Dataset Viewer
Auto-converted to Parquet
Proverbs
stringlengths
8
373
Labels
int64
0
1
Adélékè ti fagi lé àwọn ìgbésẹ̀ kan lẹ́yìn tó gbàjọba.
0
‘‘Ó kù díẹ̀ kí n wí’’: ojo ní ń sọni da.
1
A kì í pè é lẹ́rú, ká pè é lóbí.
1
A dán mi wò láti lù ú padà, ṣùgbọ́n mo kó ara mi ní ìjánu.
0
Ẹ̀bìtì ò peèrà; ará ilé ẹni ní ń pani.
1
Akínwándé ní Bíọ́dún nìkan ló lérò gidi fún ìlú yìí.
0
Ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí a níláti ṣe ni kí kálukú wa ó mọ inú ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.
0
Akáyín le j'ọgẹdẹ; kò leè jèkùrá.
1
Àgbàlagbà ńfìbínú lọ sÍlọrin, a ní kó ra tìróò bọ̀.
1
Ó ń rúgbó bọ̀ láàárín ìjọba àpapọ̀ àtàwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́.
0
Ajá tó lè sáré là ń dẹ sí egbin.
1
Bí ikú yóò pani á gbọ́ tẹnu ẹni; òpìtàn ní ń fi ìtàn gba ara-a rẹ̀ kalẹ̀.
1
Ẹfúnṣetán ń pa àwọn ẹrú rẹ̀ bi ejò àìjẹ.
0
Àtíòro-ó jẹ̀gbá jẹlá, ó ní òun ò kú; ó ní bí gbogbo ẹyẹ ayé ti ń fò náà ni òun ń fò yí.
1
Á dára tí àwọn ọlọ́pàá Nàìjíríà bá lè ṣe àtúnṣe.
0
Bí òní ti rí, ọ̀la ò rí bẹ́ẹ̀; ni babaláwo-ó fi ń dÍfá lọ́rọọrún.
1
A kì í gbé àárín ojì èèyàn ká má ṣì wí.
1
Àwọn kan sá àsálà fún ẹ̀mí wọn láìdúró ti ilẹ̀kùn ṣọ́ọ̀bù wọn.
0
Ẹní p'Òbúko fálejò, ó sì kàrà tí yóò dàá.
1
Bí ẹlẹ́bọ ò bá pe ẹni, àṣefín ò yẹni.
1
Ilé ìfowópamọ́ mọ bí ó ṣe àwọn ṣe lè wá àwọn oníjìbìtì.
0
Èèrà lóun jẹ, jẹ, jẹ òun șu, șu, su. mélòó lèèrà, tó ń jẹ, ję, jẹ, tóń su,su,su?
1
Ejò tí kó roníi re níí sanni látàrí.
1
B'ínú tì ń bí Ajànàkú náà nínú n bí Èèrà.
1
Ẹrín ò jẹ wọn ó mọ ìbínú eléyín-gan-an-gan.
1
Adégbémilé sọ pé ìrìnkurìn pọ̀ lẹ́sẹ̀ ìyàwó òun.
0
Àjẹ́gbà ni ti kọ̀m̀kọ̀.
1
Àjọṣepọ̀ wò ló wà láàrin ọ̀gagun tuntun Bọ́lájí àti Ajíbọ́lá?
0
Wọ́n kàn kẹ́ òkú ọlọ́dẹ ọ̀hún si abẹ́ igi ni.
0
Àlàó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti pèsè iṣẹ́ fún àwọn ènìyàn.
0
Ọ̀rọ̀ òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti lágbára báyìí.
0
Bí àlááfíà yóò ṣe wà láàrin àwọn Yorùbá ni Ooni bá Ààrẹ sọ.
0
Efe d'ẹfẹ ìyàn, “gbá mi létí, kí n gba ẹrú-ișu.”
1
Àwọn àáfà gbàdúrà fún àlàáfíà orílẹ̀-èdè Nàíjíríà.
0
Ajá tí ò létí ò ṣé-é dẹ̀gbẹ́ .
1
Bí a bá mọ nnkán-an fì pamọ búrúbúrú, kí a níra ení mọ o wáláwàárí.
1
Abiyamọ́ ṣọwọ́ kòtò lu ọmọ-ọ rẹ̀.
1
Wọ́n sọ pé Bọ́lá mọ̀-ọ́n-mọ̀ yọ̀ǹda lára owó ọ̀hún fún àwọn aláṣẹ ìjọba ilẹ̀ òkèèrè.
0
Mò ń gbìyànjú láti yẹra fún obìnrin náà.
0
A rìn fàà lójú akẹ́gàn; a yan kàṣà lójú abúni; abúni ò ní okòó nílé.
1
Erù omo qjeje, bibà ló bani, ki í pànìyàn (pani)
1
Ẹni tí kò bá dá wa lóhùn lẹ́yìn tí a bá dá a dúró ni a máa ń fi kòbókò nà.
0
Àrùn mẹfà ló ń pàgbà: kò jẹ, kò mu, kò șu, kò tọ, kò sùn, kò wo.
1
Àwọn ọlọ́kadà yòókù ṣàfiyèsí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n rí akẹgbẹ́ wọn.
0
Àbámodá kì í kú.
1
A kò gbọdọ̀ gbàgbé ọ̀rọ̀ egbògi olóró tí wọ́n ní Túndé Ilé-ẹrù gbé o.
0
Abíọ́lá sọ wí pé àwọn alátakò àwọn kò sọ̀rọ̀ nípa ìlera Bọlá.
0
Ẹnìkan kan ilẹ̀kùn bí Ọláwálé ti ní kí òun bọ́ sí orí ibùsùn.
0
Ajíjobì kì í ráre.
1
Bí a bá láláàfíà, a kì í wa fíafia kirí.
1
Àrùn máa ń jẹyọ lára láàárín ọjọ́ márùn-ún.
0
Àwọn ọ̀daràn wá ṣe ọṣẹ́ ní agbègbè ọ̀hún ní àsálẹ́ ọjọ́ Àìkú.
0
Ẹlòmíràn sọ pé irọ́ ni wọ́n ń pa nípa pé wọ́n bá àwọn nǹkan ètùtù nínú ọkọ̀ náà.
0
A kì í mọ alájá ká pè é ní títà.
1
Àikì í f'ojú rinjú Ọlọjà(Ọba) méjì ló ń kógún (wá) jàlú.
1
Àdúgbò mẹ́ta yóò jẹ nínú àǹfààní yìí yàtọ̀ sí Bodè àti Gáà.
0
Àwọn òṣèrébìnrin ṣe àgbékalẹ̀ ètò ìtọ́jú fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin.
0
Ariwo adìẹ yìí ti kó ìdààmú bá àwọn ènìyàn àdúgbò náà.
0
Gbogbo eye kọ ló ń jẹ jéró.
1
Bí ilé kò bá kan ilé, wọn kì í jó àjóràn.
1
Funfun kò jẹ kí á mọ òbu nínú ẹyin, àilóògùn ònmọ; kò jẹ k'á mọadélébo tó ń sàgbèrè.
1
Ó ṣọ̀wọ́n nínú olóṣèlú tó máa ń sọ òtítọ́.
0
Àjẹ́ ń ké, òkùnrùn ò paradà; ó lówó ẹbọ nílé.
1
Awakọ̀ akẹ́rù kan ló fi ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ sí i tó àwọn ọlọ́pàá.
0
Bùkọ́lá rọ ìjọba àpapọ̀ láti tètè dá àwọn padà sílé.
0
Àwọn ènìyàn jalè nídìí ẹ̀rọ tó ń sanwó ní ilé ìfowópamọ́.
0
Àwọn kan ní olóògùn ni Ìgbòho.
0
Ilé ìfowópamọ́ àgbáyé ní iye tó ń lọ sí ìwà ipá tó ń wáyé ní ọdún kan tó ìdá mẹ́wàá.
0
Àjọ èlétò ààbò ṣe ìpàdé ní olú ilé iṣẹ́ wọn.
0
Àwòdì òkè tí ń wo ìkaraun kọ̀rọ̀, kí ni yó fìgbín ṣe?
1
À ń já ìbàǹtẹ́ ẹ̀ lẹ́hìn, ó ń já tará iwájú.
1
Àìlówólọ́wọ́ kì í ṣàìsàn; àìníṣẹ́ lọ̀ràn.
1
B'éèyán bá mọojẹ, a kì í tún fií nù ún.
1
Olùkọ́ tí yóò bá ṣe àṣeyege níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ gbọ́dọ̀ palẹ̀mọ́ gidigidi.
0
Ààrẹ àwọn ọ̀dọ́ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú ọlọ́gẹ̀dẹ̀ ti ń bọ̀.
0
Bí àlejò bá ju oníle lọ, ìbòsí orò làá fi í lọ o.
1
Agbẹjọ́rò Àfáà Babátúndé láwọn ṣetán láti yí ìdájọ padà.
0
À ń pòyì ká apá, apá ò ká apá; à ń pòyì ká oṣè, apá ò ká oṣè; à ń pòyì ká kàǹga, kò ṣé bínú kó sí.
1
Ọ̀nà láti rí owó fún orílẹ̀-èdè ni epo rọ̀bì jẹ́.
0
Ení kú (lo) pe'ra ẹ lágbà.
1
B'ígi bá ń ya pàlàkà ló ti ń pète erúkọ.
1
Kọmiṣánnà sọ̀rọ̀ lórí obìnrin àti ìgbáyé-gbádùn àwọn ọmọdé ní ìpínlẹ̀ Èkìtí.
0
Ẹni tí 'ò rà kì í san.
1
Àìlówó lọ́wọ́, àìsàn kan ni.
0
Àwọn ará ì̀lú ń gbàdúrà ìyípadà rere fún orílẹ̀-èè Nàìjíríà.
0
Àìlọ́ràá àkàlàmàgbò, a ò lè fi wé ti àtíòro.
1
Bí a ti ń lọ tí à ń bọ̀ ibi kan náà ni a já sí
0
B'árá-ilé 'ò fẹràn ẹní a sì máa b'árá-àdúgbò ș'ọrẹ, a à sì máa pa ìmoràn pọ.
1
Á jẹ́ wí pé àwẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ bí wọ́n bá fi rí oṣù lónìí.
0
Bí wọn peni l'ábìfun-rài-rài; ń șe là á pà'fun ọhún mọ.
1
Àwọn akẹgbẹ́ Ṣadé ti padà sí ilé ìwé, ṣùgbọ́n Ṣadé kò bá wọn wọlé.
0
Bí ọmọdé ò kú, àgbà ní ńdà.
1
Àwọn ènìyàn tí ó fi orúkọ wọn sílẹ̀ ti lé ní mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún-lé -ní-méje ní orilẹ̀-èdè Nàìjíríà.
0
Alátiṣe ní mọ àtiṣe ara-a rẹ̀.
1
A-sọ-aré-dìjà ní ń jẹ̀bi ẹjọ́.
1
Ete awo l'ete ogberi.
1
Àwọn aṣòfin méjì mìíràn kín gbogbo àwọn tó sọ̀rọ̀ ṣáájú lẹ́yìn.
0
Elékèé lèké ń yé; oun a bá ṣe ní ń yéni.
1
Abíọ́dún kópa ribiribi ní ilẹ̀ òkèrè.
0
B'ónísègùn-ikà bá ríbi rò, yóó jàre eni t'ó fiwọ pa.
1
End of preview. Expand in Data Studio
README.md exists but content is empty.
Downloads last month
61