text
stringlengths 1
44.6M
|
---|
Tako ìfé-inú Àlàmú, ó rí i pé òun ti ń fi àwòrán nǹkan hàn Làbákẹ́ lọ́nà tààrà àti ẹ̀bùrú. |
Àlàmú ń ṣe gbogbo ohun tó ṣeéṣe láti bíi nínú, láti dà á láàmú. |
Chutni sọ bí àìsí àtìlẹ́yìn tó késejárí ṣe mú u nira láti jà tako ìwà pálapàla yìí. |
Ní Taiwan, àgbékalẹ̀ẹ ọnà alágbára kan tí a gbé sí àárín gbùngbùn Taipei ń ṣe ìrántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún-un 1989. |
Ẹ dúró dìgbà tí màá sọ ìda rẹ̀ fún yín -- ìdá mọ́kàn-lé-láàdọ́ta (61%). |
Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nínú rògbòdìyàn àjàkálẹ̀-àrùn ibà Ebola ọdún-un 2018 ní DR Congo, àwọn àyẹ̀wòkan àyẹ̀wòkàn tí a ṣe ní ara àwọn ẹni tí ó ti lu gúdẹ àrùn Ebola "tí ó tẹ̀lé àlàkalẹ̀ ìwà-ọmọlúwàbí kan" — lábẹ́ ìtọ́nàa Oníṣègùn Muyembe àti ìjọba orílẹ̀-èdèe DR Congo — dóòlà ẹ̀mí àwọn ènìyàn níkẹyìn. |
Wọ́n pa ohùn mọ́ mi lẹ́nu! |
Famalay kì í bẹ̀rù láyé láti tì ọ́ lẹ́yìn ní ìgbà gbogbo... |
O ní láti tẹ̀lé àwọn ọmọ orílẹ̀-ède South Africa, Zimbabawe, Ghana, Nigeria. |
Tí wọn ò bá ní àjọṣepọ̀ tààrà tàbí ànfàní látara àwọn ẹranko náà, wọn ò ní ìdí kankan láti dáábò bò wọ́n. |
Síbẹ̀síbẹ̀, mo ti jìyà nítorí ìwà pálapàla yìí. |
Ó ti rí ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn Sènábù láti ọ̀kánkán bí wọ́n ṣe ń bọ̀ láti ọjà. |
Ayàwòrán náà gba ìpè àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn-in ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lẹ́yìn tí ó túwíìtì àwòrán náà pẹ̀lú wípé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó mú un wálẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni CHRD ṣe ti sọ. |
Àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n ṣe ò ju kí wọ́n ba ti ènìyàn jẹ́. |
Ìṣọdẹ-àjẹ́ ṣì ń gba ẹ̀mí àwọn ènìyàn ní ìgbèríko India |
Síbẹ̀, tí a bá ti ọ̀nà ìṣe-àti-àsà wò ó, ó ṣe kókó láti sọ wí pé ìtúmọ̀ ayaba and ọbabìnrin yàtọ̀ síra wọn: Ọbabìnrin túmọ̀ sí "queen" lédè Gẹ̀ẹ́sì nígbà tí ayaba jẹ́ "wife of the king". |
Làbákẹ́ padà bẹ̀rẹ̀ si í tún ara rẹ̀ bi. |
VPN mìíràn tí ó ní ìlànà ààbò tó yàrá ọ̀tọ̀ lè jẹ́ ti ọ̀daràn. |
Làbákẹ́ tú èrò ọkàn rẹ̀, pẹ̀lú ìbínú sín ǹ kan tí ó pè ní àìṣòtítọ́ nínú àníyàn àti fọ ara rẹ̀ mọ́. Inú Àdìó sì dùn. |
Pakistan is not only about terrorism and a conservative society there is more to us. |
Adẹ́tẹ̀ẹ́ ní òun ò lè fún wàrà, ṣùgbọ́n òún lè yí i dànù. |
Á rẹ́rìn-ín músẹ́ jẹ́jẹ́, á máa wojú yín bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀. |
Fúnmi lọ́jọ́ méjì sí mẹ́ta. |
[Ìsàlẹ̀] Kò tó [lá ti yọ ọ́] nìkan, Ààrẹ tí kò ka nǹkan sí náà gbọdọ̀ jẹ́ yíyọ kúrò nínú ìṣàkósọ gbogbo kí ojú rẹ̀ le wálẹ̀. |
Èyí ni ìdí kan pàtàkì tó fi jẹ́ pé ìyá ní ó lọmọ lóòótọ́. |
Akọ̀ròyìn Esdras Ndikumana túwíìtì: |
Òǹkọ̀wé tí í ṣe ọmọ bíbí orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà Adaobi Tricia Nwaubani làdíi rẹ̀ fún àgbáyé lórí ètò ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ kan tí ó jẹ́ àbáṣepọ̀ pẹ̀lú BBC, wípé ìrísíi Trump gẹ́gẹ́ bí "ọkùnrin alágídí" mú kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ènìyàn jù lọ ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ó fẹ́ràn-an rẹ̀ dé góńgó: |
Bótilẹ̀jẹ́pé 2FA ń fún ni ní ààbò tó péye fún ìfẹ̀rílàdí, ewu àtìmóde ìṣàmúlòo rẹ le è wáyé, fún àpẹẹrẹ, o kò mọ ibi tí o ṣ'ọwọ́ọ̀ ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ sí tàbí o ti pàdánùu rẹ, tàbí pààrọ̀ ike pélébé SIM rẹ, tàbí rìnrìn àjò sí ìlú mìíràn láì tan ìrìn-káàkiri orí ẹ̀rọọ̀ rẹ. |
Ojúlé ìṣàsopọ̀ ẹ̀rọ-ayélujára |
Láti wá mọ̀ wí pé a ṣẹ̀ ń mẹ́yẹ bọ̀ lápò ni pé tí ẹ bá ṣàfiwée gbogbo ǹkan níbí sí orílẹ̀-ède South Africa, ó kọ̀ funfun ni, nítorí ní orílẹ̀-ède South Africa, ní ọdọọdún ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀rìn-dín-nírinwó (300,000) àwọn ìyá tí wọ́n ní kòkòro apa sójà ara ni wọ́n bímọ. |
Gẹ́gẹ́ bí obìnrin, kò ní ọkàn láti kojú ìgbáyàsókè ayé àti ìṣòro. |
Ní orílẹ̀-èdèe Côte d'Ivoire ní ọjọ́ 6, Oṣù kẹrin, àwọn afẹ̀hónúhàn ti iná bọ ibi àyẹ̀wò àrùn COVID-19 kan, ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni wí pé agbègbè tí èró pọ̀ sí ni wọ́n sọrí ibi àyẹ̀wò náà sí tí kò sì bójúmu. |
Bó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìmọ̀-ẹ̀rọ ṣì ń dàgbà sókè nínú ìmọ̀ rẹ̀, ó wà káàkiri. |
Làbákẹ́ nìkan kọ́ ló dájọ́ rẹ̀ báyìí. |
Àwọn alákòóso láǹfààní láti lò o. |
Á dáwọ́ dúró díẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ń dáwọ́ dúró pátápátá nígbà tí oorun ti ń kún ojú rẹ̀. |
Idà ń wó ilé ara ẹ̀ ó ní òún ń ba àkọ̀ jẹ́. |
“Hùn...hùn...” “Àwọn ìdáhùnsi ìmúnibínú ńkọ́? |
Tàbí ẹni tí ó mọ̀ nípa ọkọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ – ọkùnrin ni, kó má jẹ̀ ẹ́ obìnrin. |
Nígbàkugbà tí Àlàmú bá wọ ilé ìtọ̀, Làbáké náà ádúró nítòsí, á máa yọjú láti ibi ihò kọ́kọ́rọ́ ilèkùn ilé ìtọ̀. |
“Bẹ́ẹ̀ ni…….bẹ́ẹ̀ ni. Mo mọ̀ pé ìwọ ni Àlàmú ……..ṣùgbọ́n…….ṣùgbọ́n.” |
Fún ìdí èyí, ó tó kí ó kúkú bẹ̀rẹ̀ sí i rẹ́rìn- ín músẹ́ láti ìsìnyí nínú ìrètí áti ìgbàgbọ́ pé gbogbo nǹkan a sìse fún rere. |
Aaka ò gbé ọ̀dàn; igbó ní ń gbé. |
Màá jókòó báyìí, á bá mi lórí ìjókòó báyìí...mo ń dúró...mò ń dúró... |
Apá ibẹ̀ nínú ìlú ni Làbákẹ́ ṣe àbẹ̀wò sí nígbà tó kọ́kọ́ dé láti ìlú òyìnbó. |
Àárín gbùngbùn Àríwá, Àríwá Ìlà-oòrùn, Àríwá Ìwọ̀-oòrùn, Àjìǹdò-gúúsù, Ìwọ̀-oòrùn gúúsù, àti Ìlà-oòrùnun gúúsù. |
Kò sí nǹkan tí wọn ó le ṣe tí òfin àti àsẹ bá dàrú. |
Nítorí orílẹ̀ èdèe tí ó gbajúmọ̀ jù lọ nílẹ̀ Adúláwọ̀ yóò yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ sí ìjọba ìfipámúnisìn ní kété tí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ bá di títẹ̀ bọlẹ̀. |
Àpò Àlàmú ń jò gidigidi, ìparí oṣù sì ń jẹ́ àsìkò fún un láti làágùn tútù, ó jẹ́ àsìkò fún un láti lejú kí ó sì ranjú bí ó ṣe ń wo ètò ìṣúná owó rẹ̀ lésẹẹsẹ̀. |
Kò gba àyà rẹ̀ ní ìṣéju mẹ́ta láti bẹ̀rẹ̀ si í mí. |
Ó yára fi òpin sí ìpè náà. |
Dídúró sílé yìí kì í se ohun tó bá àwọn onísẹ́ ọwọ́ àti oníṣẹ́ ìgbẹ́mìíró tí ó ń gbé ní Mozambique àti Cape Verde lára mú rárá. Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ-ènìyàn Tomás Queface túwíìtì: |
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn tí ò sí ní abẹ́ ìṣàkóso ìjọba Novaya Gazeta ti ṣe sọ, ó yẹ kí ètò náà tí yóò ṣe àfihàn àwọn ajìjàǹgbara LGBT ní Yaroslavl wáyé ní òwúrọ̀ Ọjọ́rú 23, ní oṣù Ṣẹẹrẹ. |
Mo ní, "Ǹjẹ́ o dárúkọ kùkúyè? |
Ǹkan tí àwọn ilé-iṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ mọ̀ nípa àwọn ọmọọ̀ yín. |
Ní ìparí ọdún 2015, ọlọ́pàá pa òǹyàwòrán Christophe Nkezabahizi pẹ̀lú àwọn ọmọ-lẹ́bí mẹ́ta, ní àsìkò ìbò tí ìfẹ̀hónú wá sáyé. |
Làbákẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ gbé kẹ́tùlù nílẹ̀... Oníkálukú sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ! |
Ilẹ̀kùn náà ṣí yàrá náà sì kún fún àwọn ìyá, àwọn ìyá tí wọ́n lọ́mọ lọ́wọ́, tí wọ́n jókòó, tí wọ́n ń sọ́rọ̀, tí wọ́n ń tẹ́tí. |
Ẹ̀gbẹ́ alájòótà yìí ti tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin abala 505(a) tí ó ní wípé ọ̀daràn ni ẹni tí ó bá polongo ọ̀rọ̀, àyesọ, tàbí jábọ̀ irúu rẹ̀ pẹ̀lú èrò láti mú kí ikọ̀ ajagun ó máà ka ojúṣe rẹ̀ kún tàbí kùnà láti ṣe ojúṣee rẹ̀. |
Bẹ́ẹ̀, kò sí àní-àní, kò sí àní-àní, ó ní láti ṣe é. |
Àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn – Yẹmí Ọṣìńbàjò (APC), ọmọ Yoruba, àti Peter Obi (PDP), ọmọ Igbo, jẹ́ Ọmọ-lẹ́yìn-in-krístì — àmọ́ láti ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. |
Ikọ̀ ẹ kú oríire! |
Àwọn aláboyún tí wọ́n ní kòkòro apa sójà ara gbọ́dọ̀ gba iṣẹ́ PMTCT láti lè ní àwọn ìkókó tí ò ní kòkòro apa sójà ara. |
Àwọn alátìlẹ́yìn-in rẹ̀ ń pè fún ìtúsílẹ̀ẹ rẹ̀ lóríi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, látàrí wípé a ti yọ àbọ̀ ẹ̀dọ rẹ̀ nítorí àrùn jẹjẹrẹ àti àrùn ọkàn àti ìṣòro kíndìnrín. |
Ó lèbínú tàpa sáṣẹ. Ó mọ bí wọ́n ṣe ń fi ojú pípọ́n hàn kí ó sì fi ẹ̀rín ṣẹ̀sín ènìyàn. |
Ó yẹ kí a tẹ̀ ẹ́ sórí ìwé tàbí kọ ọ́ sílẹ̀ kí a máa gbé e kiri. |
Ìjìyà yóò wá sópin |
Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó dára, ilé àdágbé tiwọn ní ìgbèríko ìlú, lọ́nà to yára kíá kíá. |
Màdáámù ti ń kanra ganan lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí. |
Ìràwọ̀ agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀-èdè Ivory Coast Didier Drogba túwíìtì: |
1. Ó gbọdọ̀ ṣe é jó sí, síbẹ̀ ó ní láti dùn ún ní etí àwọn ènìyàn tí yóò “mú wọn gbàgbé ara” ní orí ìtàgé, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ orin tí yóò mú ayọ̀ jáde, èyí tí a mọ Ijó ìta-gbangba mọ́. |
"I Have a Red in My Wipe" clip tẹ́lẹ̀. |
Boniface Igbeneghu, ọ̀jọ̀gbọ́n Ifásitìi Èkó, Nàìjíríà ti bá ẹni tí ó wọ ìbòjú yìí ṣe erée gélé ní àìmọye ìgbà (Àwòrán láti BBC #SexForGrades) |
" Ó kàn sí mi lẹ́yìn òsẹ̀ méjì pẹ̀lú ìwé yìí: ìdókówò mi àkọ́kọ́ nínú ìpín ìdókówò ilẹ̀-òkèrè jẹ́ ti British America Tobacco. |
“Ṣé o mọ̀ bóyá ó ní ìṣoro kankan?” |
Níbi ìpàdé kan láàárín àwọn méjèèjì, Igbeneghu ṣẹ́ iná pa, ó sì ní kí ọmọdébìnrin náà ó fẹ́nu ko òhun lẹ́nu, tí ó sì tún dì mọ́ ọn gbádígbádí nínúu iyàraa iṣẹ́ẹ rẹ̀ tí ó wà ní títì pa. |
Nígbà tí wọn kọ́kọ́kó wọ inú ilé náà ní kété tí wọn ṣègbeyàwó, ó wà pẹ̀lú ìrètí gíga láti sọ ilé náà di párádísè. |
Àwọn méjì gbòógì òǹdíjedupò sí ipò ààrẹ, Ààrẹ tí ó wà lórí àléfà kó ìbò ẹgbẹẹgbẹ̀rún 15 tí ó mú u borí olórogún-un rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí, Atiku Abubakar, pẹ̀lú "àlàfo idà 56 sí ìdá 41". |
Kò kàn án bín-in-tín báyìí. |
Wọ́n ń tọpa wọn pẹ̀lú àwọn ìkànì ètò-ẹ̀kọ́ àti àwọn ìmọ̀-ẹ̀rọ ètò-ẹ̀kọ́ ní ilé-ẹ̀kọ wọn. |
Fi àyè gba àwọn ẹ̀rọ-ayárabíàṣá mìíràn lórí ìṣàsopọ̀ yìí láti ṣàgbéwọlé àwọn ìkànnì mi tí kò sí lákàálẹ̀. |
Èyí kò gbé mi lọ́kàn bíi ti ìlàkàkà àwọn ọmọ-adúláwọ̀ tí ó ń ṣe ìrìnàjò nínúu ilẹ̀-adúláwọ̀. |
Síbẹ̀, òtítọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò ní ohun-èlò, tí kò sí àyèwò àti ìtọ́jú, ìda ogójì -- ìda ogójì àwọn ọmọ ni wọ́n ní i -- ìda ogójì kojúu ìdá méjì – ìyàtọ̀ tó pọ̀ gidi gan. |
Nígbà tí àwọn ara ìlu Burundi sá fún wàhálà òṣèlú, wọ́n wá báwa, sí àwọn orílẹ̀-èdè tókù nílẹ̀ Adúláwọ̀. |
Sènábù ṣàlàyé fún màmá pẹ̀lú ọkàn mímó àìlẹ́bí àti omijé lójú rẹ̀. |
Óyá gbìyànjú ẹ̀. |
Ọjọ́ ìbànújẹ́ àti wàhálà rẹ̀ ti níye. |
Obama ni wá, Garvey ni wa, Marley ni wa, Angelou ni wa, Walcott ni wa. |
Ìfòfinde ìsoyìgì pẹ̀lú ọmọdé máa ń fi ààbò fún àwọn ọmọdébìnrin, láì ro bí wọ́n ṣe wọ ilé ìwé. |
Ọ̀kanòjọ̀kan ọnà ni ó wà ní ara ilé náà — àwọn àràbarà ọnà abẹ́ àjà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. |
Òfin ni yó sọ ara ẹ̀; ìyàwó tí ń na ọmọ ìyáálé. |
Àwa, tí a wà nínú ìlú, ni a ó fi ààbò bò tí a ó sì ké pe àwọn aráa wa ní òkè òkun, kí àwọn náà ó ké gbàjarè, nítorí ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà ṣe kókó fún wọn. |
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, ìjọba Burundi ti ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn lábẹ́ United Nations tí wọ́n sì sọ pé àwọn kò nílòo wọn mọ́. |
Ní báyìí, kò sí ọ̀nà tí èyí fi jẹ́ àwíjàre fún ìwà-ìbàjẹ́. |
Àwọn oníkọkúkọ ní ìṣọ̀kan |
Transgender Pride march takes place in Pakistan |
Ọmọ rẹ̀ tí ó mọ̀, lọ́kàn ara rẹ̀ ti lọ sí ìrìnàjò àrèmabọ̀. |
Mo dẹ̀ ní ìdánilójú pé pẹ̀lú àjọṣepọ̀ tó tọ́, a máa ṣègun ààrùn burúkú yìí. |
Àwọn méjèèjì kàn ṣáà ń níì gbàmọ́ra àti ìfaradà fún ara wọn ni. |
Ní kò pẹ́ kò pẹ́ yìí ni ìwádìí àyẹ̀wò tí Pew Research Centre ṣagbátẹrùu rẹ̀ fi hàn wípé ọ̀gọ̀rọ̀ ọmọ Nàìjíríà "fi Ògún-un rẹ̀ gbárí" wípé Trump "yóò gbé ìgbésẹ̀ tí ó lààmìlaka nípa ti ọ̀ràn àgbáyé". |