translation
dict
{ "en": "Feminist Cecília Kitombé reacted to those who continue to encourage violent relationships:", "yo": "Ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin Cecelia Kitombé sọ̀rọ̀ sí àwọn tí ó ń ṣe àtìlẹyìn ìbáṣepọ̀ tí ó níyà nínú:" }
{ "en": "Translation Original Quote", "yo": "Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an" }
{ "en": "Some of those who are … asserting that it is too much [to speak out against domestic violence], are the same who advise daughters, sisters, and cousins to stay in abusive relationships, under the pretext that in the conversation of husband and wife you cannot interfere, and others tell you to continue, life in a couple is just like that...", "yo": "Lára wa tí à ń tẹnumọ́ ọn pé ó pọ̀jù [láti sọ̀rọ̀ síta tako ìjìyà Abẹ́lé] náà ni ẹni tí ó ń gba àwọn ọmọbìnrin, arábìnrin àti ìbátan lóbìnrin níyànjú láti máa fi ara da ìbáṣepọ̀ tí ó ń pani lára pẹ̀lú ọ̀rọ̀-ẹ̀tàn pé ọ̀rọ̀ tọkọtaya ò ṣe é dá sí, àwọn mìíràn á ní kí o tẹ̀síwajú bẹ́ẹ̀, bí ọ̀rọ̀ lọ́kọláya ṣe rí nìyẹn..." }
{ "en": "There are also those who think that women can do everything, but must never forget their \"role\"", "yo": "Àwọn kan tilẹ̀ rò pé obìnrin lè ṣe gbogbo nǹkan, ṣùgbọ́n wọn ò gbọdọ̀ gbàgbé \"ojúṣe\" wọn." }
{ "en": "Stop killing us!!!", "yo": "Ẹ yéé pa wá!!!" }
{ "en": "How preserving folktales and legends help raise environment awareness in the Mekong", "yo": "Bí àpamọ́ àlọ́ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ ṣe mú ọ̀rọ̀ àyíká di mímọ̀ ní Mekong" }
{ "en": "The Mekong Basin. Photo from the website of The People's Stories project.", "yo": "Adágún omi Mekong. Àwòrán tí a mú láti Ibùdó-ìtàkùn-àgbáyé iṣẹ́ Ìtàn Àwọn Ènìyàn." }
{ "en": "Used with permission", "yo": "A lò ó pẹ̀lú àṣẹ." }
{ "en": "In 2014, several indigenous communities in the Mekong started recording their stories and legends with the help of a group of researchers who are exploring how these narratives can help exposing the destructive impact of large-scale projects in the region.", "yo": "Ní ọdún 2014, ogunlọ́gọ̀ ìbílẹ̀ ní Mekong bẹ̀rẹ̀ sí ní í ṣe àkọsílẹ̀ àwọn àlọ́ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ wọn pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹgbẹ́ aṣèwádìí kan tí ó ń ṣe àyẹ̀wò fínnífínní sí bí ìtàn wọ̀nyí ṣe lè ṣe ìrànwọ́ tí yóò tú àṣìírí ìmúdìbàjẹ́ àyíká tí àwọn iṣẹ́ ńláǹlà ń fà ní agbègbè náà." }
{ "en": "The Mekong is one of Asia’s great river systems which flows through six countries: China, Myanmar, Thailand, Laos, Cambodia, and Vietnam.", "yo": "Mekong jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn odò ńlá Ásíà tí ó ṣàn gba orílẹ̀-èdè mẹ́fà: China, Myanmar, Thailand, Laos, Cambodia, àti Vietnam." }
{ "en": "It is rich in biodiversity and a vital source of livelihood for millions of farmers and fisherfolk.", "yo": "Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ ìṣẹ̀dá abẹ̀mí àti ewéko tí ó jẹ́ ohun ìsayéró fún ẹgbẹẹ̀gbẹ̀rún àgbẹ̀ àti apẹja." }
{ "en": "In recent years, several large-scale projects such as hydropower dams have displaced residents while threatening the river basin's ecosystem.", "yo": "Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ńláǹlà bíi kòtò ìdarí-omi ṣíṣàn fún Ìpèsè Iná Mànàmáná ti lé àwọn olùgbé jìnà ó sì ń ṣe àkóbá fún nnkan ìṣẹ̀dá odò náà." }
{ "en": "Despite protests, the construction of dams has continued, especially in Laos and Thailand.", "yo": "Ọ̀kanòjọ̀kan ìfẹ̀hónúhàn kò ṣe nǹkan kan, àwọn iṣẹ́ ìdarí-omi ṣíṣàn ṣì ń lọ, pàápàá jù lọ ní Laos àti Thailand." }
{ "en": "In partnership with Mekong Watch, a Japan-based group advocating sustainable development in the region, several community elders in the Mekong began recording some of their stories and legends in 2014 that revolve around nature.", "yo": "Pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Mekong Watch, ẹgbẹ́ kan ní Jápáànì ń jà fún ìdàgbàsókè ní agbègbè náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbà ní Mekong ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ wọn tí ó ní íṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀dá." }
{ "en": "Mekong Watch believes that these stories \"have played an important role in protecting nature by avoiding the over-exploitation of natural resources.\"", "yo": "Mekong Watch gbàgbọ́ wípé àwọn ìtàn wọ̀nyí \"ti kó ipa ribiribi ní ti ìdáàbò ìṣẹ̀dá nípa dídẹ́kun ìwà àìbìkítà fún ọrọ̀ ìṣẹ̀dá.\"" }
{ "en": "Mekong Watch asserts that part of the commons that need to be protected are not just natural resources but also \"intangible heritages\" that can be shared and accessed by the local community.", "yo": "Mekong Watch sọ wípé ohun ìṣẹ̀dá nìkan kọ́ ni a ní láti dáàbò bò àmọ́ àti àwọn \"nǹkan àjogúnbá tí-a-kò-le-è-rí-dìmú\" tí a lè pín àti rí lò." }
{ "en": "Toshiyuki Doi, senior adviser of Mekong watch, adds:", "yo": "Toshiyuki Doi, olùdámọ̀ràn àgbà fún Mekong Watch, ní èyí láti sọ:" }
{ "en": "People’s stories should be regarded, recognized, and respected as Mekong’s commons, especially these days when they are losing their place in local communities to more modern media, and are not passed on to next generations.", "yo": "Ó pọn dandan fún wa láti ka ìtàn àwọn ènìyàn Mekong kún, kí a dá wọn mọ̀, àti bọ̀wọ̀ fún wọn, papàá jù lọ ní òde òní tí wọ́n ti ń pàdánù àyè wọn ní ìrọ́pò ilé iṣẹ́ oníròyìn ìgbàlódé, tí wọn kò sì fi àjogúnbá lé ìran tí ó ń bọ̀ lọ́wọ́." }
{ "en": "Areas in the Mekong where researchers conducted fieldwork. 1. Kmhmu’ in northern and central Laos; 2. Siphandon in southern Laos; 3. Akha in northern Thailand; 4. Thai So and Isan in northeastern Thailand; 5. Bunong in northeastern Cambodia.", "yo": "Àwọn agbègbè ní Mekong níbi tí àwọn oníṣẹ́-ìwádìí ti ṣe iṣẹ́. 1. Kmhmu’ ní àríwá àti àárín gbùngbùn Laos;; 2. Siphandon ní gúúsù Laos; 3. Akha ní àríwá Thailand; 4. Thai So atí Isan ní àríwá-ìwọ̀-oòrùn Thailand; 5. Bunong ní àríwá-ìwọ̀-oòrùn Cambodia." }
{ "en": "Used with permission.", "yo": "A lò ó pẹ̀lú àṣẹ." }
{ "en": "The group was able to collect a total of 102 stories in Cambodia, Laos, and Thailand.", "yo": "Ẹgbẹ́ náà ṣe gudugudu méje yàyà mẹ́fà kí ó tó kó oríṣiríṣi ìtàn 102 jọ ní Cambodia, Laos, àti Thailand." }
{ "en": "Stories were recorded, transcribed, and translated into the national languages of Thailand, Laos, and Cambodia before an English version was made.", "yo": "A ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìtàn wọ̀nyí, dà á kọ sílẹ̀ sínú ìwé, àti ìtúmọ̀ ìtàn sí àwọn èdè orílẹ̀ Thailand, Laos, àti Cambodia kí ó tó kan ẹ̀da ti èdè Gẹ̀ẹ́sì." }
{ "en": "Mekong Watch published these stories as pamphlets in both printed and digital formats, and used them during environment workshops they conducted at the communities.", "yo": "Mekong Watch tẹ àwọn ìtàn wọ̀nyí jáde sórí ìwé ìròyìn pélébé àti sórí ẹ̀rọ ayárabíàṣá, wọ́n sì tún lò ó ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa àyíká ní àwọn ìlú náà." }
{ "en": "Since late 2016, we have used people’s stories to provide environmental education to children in rural Laos and Thailand.", "yo": "Láti ìparí ọdún 2016, a ti fi ìtàn àwọn ènìyàn ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àyíká fún àwọn èwe ní ìgbèríko Laos àti Thailand." }
{ "en": "We have hosted workshops in schools and local communities to guide children, and sometimes adults, to collect stories from elderly people, learn from the stories, and turn them into reading materials.", "yo": "A ti ṣe àgbékalẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìwé àti ní ìlú ìbílẹ̀ láti tọ́ àwọn èwe sọ́nà, àti àwọn àgbà nígbà mìíràn, láti ṣe àkọsílẹ̀ ìtàn ẹnu àwọn àgbàlagbà, fi ìtàn náà kọ́gbọ́n, àti láti sọ wọ́n di kíkà." }
{ "en": "An example of a workshop involves the retelling of the story of \"The Owl and the Deer\" from Kmhmu’ people in central and northern Laos.", "yo": "Àpẹẹrẹ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan ni ìtúnsọ àlọ́ ‘Òwìwí àti Àgbọ̀nrín‘ àwọn aráa Kmhmu ní àárín gbùngbùn àti àríwá Laos." }
{ "en": "The story is about an owl who lost his ability to see during the day after cheating a deer.", "yo": "Àlọ́ náà dá lóríi òwìwí tí kò ríran ní ọ̀sán nítorí ó yan àgbọ̀nrín jẹ." }
{ "en": "During a workshop, young participants are asked:", "yo": "Níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan, a bi àwọn èwe tí ó kópa:" }
{ "en": "\"What kinds of animals appear in the story?\",", "yo": "\"Irúfẹ́ ẹranko wo ni a bá nínú àlọ́ náà?\"," }
{ "en": "\"Can you see these animals in your village?\", and", "yo": "\"Ǹjẹ́ a lè rí àwọn ẹranko wọ̀nyí ní abúlée yín bí?\", àti" }
{ "en": "\"If there are fewer of these animals in your village than before, why do you think this has happened?\"", "yo": "\"bóyá àwọn ẹranko wọ̀nyí ti dínkù sí ti ìgbà kan, kí ni ìwọ rò wípé ó ti ṣẹlẹ̀?\"" }
{ "en": "After this, participants are encouraged to connect the story to the deterioration of the environment in their communities.", "yo": "Lẹ́yìn èyí, a gba àwọn akópa ní ìyànjú láti so àlọ́ náà mọ́ ìdìbàjẹ́ àyíká ní ìlúu wọn." }
{ "en": "In Champasak Province, south Laos, the legend of the endangered Irrawaddy dolphin and the Sida bird is used to highlight how a dam project is disrupting the seasonal migration of Mekong River fisheries.", "yo": "Ní agbègbè Champasak, gúúsù Laos, ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ ẹranko omi tí ó ti ń dínkù Irrawaddy dolphin àti ẹyẹ Sida ni a ń lò fi ṣe àpèjúwe bí iṣẹ́ ìdarí-omi-ṣíṣàn ṣe ń ṣe àkóbá fún ẹja inú odò Mekong." }
{ "en": "Another story also from southern Laos is instructive on the value of resource management:", "yo": "Àlọ́ mìíràn láti gúúsù Laos ní àwọn ìlànà tí ó kọ́ni nípa ìmọrírìi ìbójútó ọrọ̀ ìṣẹ̀dá:" }
{ "en": "The story about the Rhino Head was recorded on November 16, 2014, at the Songkram River bank in northeast Thailand.", "yo": "A ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ Orí Erinmi ní ọjọ́ 16, oṣù Belu, ọdún 2014, ní etídò Songkran ní àríwá-ìwọ̀-oòrùn Thailand." }
{ "en": "The narrator was Mun Kimprasert, aged 68, photo by Mekong Watch, used with permission.", "yo": "Mun Kimprasert, ẹni ọdún 68. ni asọ̀tàn, Mekong Watch ló ni àwòrán, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ." }
{ "en": "Once, a soldier stepped into a spirit forest.", "yo": "Ní ìgbà kan, ológun kan wọ inú igbó iwin kan." }
{ "en": "He discovered a lot of tobacco leaves there and collected them.", "yo": "Ó ṣe alábàápàdé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewé kátabá níbẹ̀ ó sì ṣẹ́ wọn." }
{ "en": "However, when trying to leave the forest, he could not find an exit.", "yo": "Àmọ́ ṣá, bí ó ti fẹ́ẹ́ jáde nínú igbó náà, ọ̀nà dí mọ́n ọn ní ojú, kò sì mọ ọ̀nà mọ́." }
{ "en": "It was because he took more tobacco leaves than he could possibly consume for himself.", "yo": "Nítorí wípé ó ṣẹ́ ewé kátabá tí ó pọ̀ ju èyí tí ó lè lò lọ ni kò fi mọ ọ̀nà mọ́n." }
{ "en": "No matter how hard he searched, he could not find a way.", "yo": "Ó wá ọ̀nà títí kò rí." }
{ "en": "Realizing what might have been the problem, he finally decided to return the tobacco leaves to the forest.", "yo": "Ẹ̀rí-ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ́ ẹ fún ohun tí ó ṣe, ó pinnu láti dá àwọn ewé kátabá náà padà sí ibi tí ó ti gbé ṣẹ́ ẹ." }
{ "en": "The moment he dropped them on the ground, he was able to see an exit in front of him.", "yo": "Wéré tí ó sọ ọ́ sílẹ̀, logan ni ó rí ọ̀nà ní iwájúu rẹ̀." }
{ "en": "In northern Thailand, a story by the Akha people about the origin of the swing teaches self-sacrifice through a heroic episode of a brother and a sister who put the world in order.", "yo": "Ní àríwá Thailand, àlọ́ àwọn aráa Akha kan nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ swing tí ó sọ iṣẹ́ takuntakun ìfaraẹnisílẹ̀ t'ẹ̀gbọ́ntàbúrò tí ó mú ayé rọrùn." }
{ "en": "In northeast Thailand, a folktale about Ta Sorn narrated by Tongsin Tanakanya promotes unity among neighbors in a farming community.", "yo": "Ní àríwá ìwọ-oòrùn Thailand, àlọ́ kan tí ó dá lórí Ta Sorn tí Tongsin Tanakanya sọ ṣe ìgbélárugẹ ìṣọ̀kan láàárín aládùúgbò ní ìlú iṣẹ́ àgbẹ̀." }
{ "en": "Another story recalls how the hunting of a rhinoceros led to the formation of salt trading in this part of the country.", "yo": "Ìtàn mìíràn ṣe ìrántí bí pípa àgbànrere kan ṣe fa iyọ̀ títà ní apá orílẹ̀-èdè yìí." }
{ "en": "In Bunong, located in northeast Cambodia, there are stories about rituals to fix bad marriages and planting and harvest ceremonies narrated by Khoeuk Keosineam.", "yo": "Ní Bunong, tí ó wà ní àríwá ìwọ-oòrùn Cambodia, àwọn àlọ́ tí ó sọ nípa ètùtù fún àtúnṣe sí ìgbéyàwó tí kò ní adùn àti ètùtù ìfọ́nrúgbìn àti ìkórè tí Khoeuk Keosineam jẹ́ asọ̀tàn." }
{ "en": "There is also the legend of the elephant as retold by Chhot Pich which reveals how villagers who once poisoned a river were punished by the gods and turned into elephants.", "yo": "Bákan náà ni ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ erin tí Chhot Pich sọ ṣe àfihàn bí àwọn òrìṣà ṣe sọ àwọn ará abúlé tí ó fi májèlé sí inú odò di erin." }
{ "en": "It explains why elephants were comfortable living with humans but, after several generations, they forgot their origins and went to live in the forest.", "yo": "Ó sọ ìdí tí ó fi rọrùn fún erin láti máa gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn àmọ́, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran, wọ́n gbàgbé ìpìlẹ̀ wọn, wọ́n lọ ń gbé nínú igbó." }
{ "en": "Hea Phoeun from the Laoka Village, Senmonorom, Mondulkiri Province in Cambodia shares a village ritual on how to fix an unfit marriage.", "yo": "Hea Phoeun ti abúlé Laoka, Senmonorom, agbègbè Mondulkiri ní Cambodia ń ṣàlàyé ètùtù ìgbéyàwó tí kò ládùn ní abúlé." }
{ "en": "Photo by Mekong Watch, used with permission.", "yo": "Àwòrán láti ọwọ́ọ Mekong Watch, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ." }
{ "en": "For Mekong Watch and the threatened communities in the region, preserving these stories is integral in the campaign to resist projects that would displace thousands of people living in the Mekong:", "yo": "Fún Mekong Watch àti àwọn agbègbè ní ìlú náà tí àkóbá ti bá, ìpamọ́ àwọn ìtàn wọ̀nyí ṣe kókó nínú ìpolongo ìkọjú-ìjà sí àwọn iṣẹ́ tí yóò lé ẹgbẹẹgbẹ̀rún olùgbé Mekong kúrò ní ilée wọn:" }
{ "en": "These stories can help form their identity as a community member and identify with the environment.", "yo": "Ìtàn wọ̀nyí lè di ìdánimọ̀ọ wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìlú àti ìbáṣepọ̀ t'ó dán mánrán pẹ̀lú àyíká." }
{ "en": "By means of stories, the communities search for ways to accommodate and/or resist changes that are taking place in the Mekong river basin.", "yo": "Nípasẹ̀ẹ ìtàn, ìlú yóò wá ọ̀nà ìgbàmọ́ra àti/tàbí ìkọjú-ìjà sí ìyípadà tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní odò Mekong." }
{ "en": "Meet Nigeria's presidential candidates of 2019", "yo": "Mọ àwọn òǹdíje sí ipò ààrẹ Nàìjíríà ọdún 2019" }
{ "en": "The 2019 Nigerian presidential candidates [Collage by Nwachukwu Egbunike].", "yo": "Àwọn òǹdíje sí ipò ààrẹ Nàìjíríà ọdún 2019 [Àkópọ̀ àwòrán láti ọwọ́ọ Nwachukwu Egbunike]." }
{ "en": "Nigeria, Africa's most populous nation, will hold presidential elections on February 16, 2019.", "yo": "Nàìjíríà, orílẹ̀-èdè tí ó ní ènìyàn tí ó pọ̀ jù ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀, yóò di ìbò ipò ààrẹ ní ọjọ́ 16, oṣù 2019." }
{ "en": "Although there are 73 presidential candidates, the race for Aso Rock — the seat of Nigeria's presidency — will be between two major contenders and candidates from the so-called \"third force\", a group of hopefuls who are relatively new to Nigerian politics.", "yo": "Bí-ó-ti-lẹ̀-jẹ́-wípé àwọn òǹdíje sí ipò ààrẹ t'ó 73, eré Àpáta Agbára – ibùjókòó ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà – yóò wáyé ní àárín-in ẹgbẹ́ olóṣèlú méjì tí ó ti ń figagbága ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́ àti àwọn òǹdíje tí a pè ní \"agbára ìkẹta\", ìyẹn àwọn ẹgbẹ́ a ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sínú ìṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà." }
{ "en": "Muhammad Buhari, president of Nigeria. Creative Commons.", "yo": "Muhammad Buhari, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Creative Commons." }
{ "en": "The two major Nigerian parties, All Progressive Congress and Peoples Democratic Party, will, of course, be fielding their candidates:", "yo": "Ẹgbẹ́ méjèèjì tí ó gbajúmọ̀ jù lọ, Ìpéjọ Ìlọsíwájú Gbogboògbò APC àti Ẹgbẹ́-olóṣèlú Ìjọba-àwa-arawa PDP, láì ṣe àní-àní, yóò tari òǹdíje wọn sí gbangba wálíà:" }
{ "en": "Muhammadu Buhari", "yo": "Muhammadu Buhari" }
{ "en": "The incumbent candidate of the All Progressive Congress, Buhari won the 2011 presidential election after defeating former president Goodluck Jonathan.", "yo": "Ààrẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ tí ó jẹ́ òǹdíje lábẹ́ àsíá APC, Buhari ló jáwé olúborí nínú ìbò ààrẹ ti ọdún 2011 tí ààrẹ ìgbà kan Goodluck Jónátánì sí pàdánù." }
{ "en": "Buhari's ascendance to power was based on his integrity and perceived ability to curb corruption and the Boko Haram militancy.", "yo": "Nítorí irú ènìyàn tí Buhari ń ṣe àti èrò wípé yóò gbógun ti ìjẹgúdújẹrá àti ìgbáwọlẹ̀ ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò Boko Haram ni àwọn ará ìlú fi gbé e sórí àlééfà." }
{ "en": "However, under his watch, Nigeria has witnessed continued insecurity with pastoral conflicts between herders and farmers as herders from the north move further south in search of arable lands.", "yo": "Síbẹ̀, lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀, ààbò ẹ̀mí kò sí pẹ̀lú ìkọlù láàárín darandaran àti àgbẹ̀ bí àwọn darandaran láti àríwá ṣe ń wọ gúúsù láti wá koríko fún ẹran ọ̀sìn-in wọn." }
{ "en": "Also, human rights have taken a nose drive in his administration, with impunity and corruption at the highest levels of government.", "yo": "Bákan náà, ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ti wó lulẹ̀ nínú ìṣàkóso ìjọba rẹ̀, pẹ̀lú àìjẹ̀yà àti ìṣowó-ìlú-mọ̀kumọ̀ku ní ibi gíga nínú ìjọba." }
{ "en": "Atiku Abubakar [Image from Campaign Organisation Website].", "yo": "Atiku Abubakar [Àwòrán Ibùdó-ìtàkùn-àgbáyé Ilé-iṣẹ́ ìpolongo]." }
{ "en": "Atiku Abubakar", "yo": "Atiku Abubakar" }
{ "en": "Abubakar is the former vice president and candidate of the Peoples Democratic Party.", "yo": "Abubakar ni igbá-kejì ààrẹ ìgbà kan àti òǹdíje lábẹ́ àsíá PDP." }
{ "en": "He has tried in the past to win presidential elections but has not been successful.", "yo": "Ó ti gbìyànjú sẹ́yìn láti di ààrẹ àmọ́ orí kò ṣe ní oore." }
{ "en": "However, his campaign received a major boost with the reconciliation with his boss, former President Olusegun Obasanjo — who had described Buhari's administration as a failed government.", "yo": "Bíótiwùkíórí, ìpolongo rẹ̀ jẹ́ ìgbàwọlé nítorí ìparí ìjà tí ó wà ní àárín òun àti ọ̀gáa rẹ̀, Ààrẹ ìgbà kan rí Olusegun Obasanjo — tí ó sọ wípé ìṣàkóso ìjọba Buhari kùnà." }
{ "en": "As vice president, Abubakar oversaw the privatization and sale of hundreds of loss-making and poorly managed public enterprises.", "yo": "Gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́, Abubakar ni ó ṣe bònkárí ìsọhun-ìjọba-di-àdáni àti títa ọ̀kẹ́ àìmọye ilé iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti ìjọba tí kò pa owó sí àpò ìjọba." }
{ "en": "A few other presidential hopefuls to watch are:", "yo": "Àwọn mìíràn tí ó ní ìrètí sí ipò ààrẹ Nàìjíríà ni:" }
{ "en": "Oby Ezekwesili [Image released by campaign organizers as media resource]", "yo": "Oby Ezekwesili [Àwòrán tí àwọn alágbèékalẹ̀ ìpolongo tari síta]" }
{ "en": "Obiageli [Oby] Ezekwesili", "yo": "Obiageli [Oby] Ezekwesili" }
{ "en": "Ezekwesili, the only major female candidate in this year's race, served as the minister of solid minerals and later education during the presidency of Olusegun Obasanjo between 1999 to 2007.", "yo": "Ezekwesili, obìnrin kan ṣoṣo tí ó ń du ipò nínú eré ìbò sísá ti ọdún tí a wà yìí, ti ṣe mínísítà ọrọ̀ líle inú-ilẹ̀ àti ètò ẹ̀kọ́ ní àsìkò ìjọba Olusegun Obasanjo ní àárín ọdún 1999 sí 2007." }
{ "en": "She was also former vice president of the Africa division of the World Bank from May 2007 to May 2012.", "yo": "Ó sì ti ṣe amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ààrẹ Ilé ìfowópamọ́ Àgbáyé ẹ̀ka ti Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ìgbà kan láti oṣù Igbe ọdún 2007 sí oṣù Igbe ọdún 2012." }
{ "en": "Ezekwesili has been at the forefront of the call to rescue about 200 school girls who were abducted by the Boko Haram militant Islamic group in 2014.", "yo": "Ezekwesili ti ṣe bẹbẹ nínú akitiyan ìdásílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́-bìnrin 200 tí ọmọ ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfo Ẹlẹ́sìn ìmale jí gbé ní ọdún 2014." }
{ "en": "She is a co-founder of the #BringBackOurGirls (BBOG) Movement.", "yo": "Ó jẹ́ ọ̀kan lára olùdásílẹ̀ Ìpolongo #BringBackOurGirls (BBOG)." }
{ "en": "She is also the presidential flag-bearer of the Allied Congress Party of Nigeria.", "yo": "Bákan náà ni ó jẹ́ òǹdíje sí ipò ààrẹ ní abẹ́ ẹgbẹ́ olóṣèlú Allied Congress Party ti Nàìjíríà." }
{ "en": "Kingsley Moghalu [Image from campaign website].", "yo": "Kingsley Moghalu [Àwòrán láti ibùdó ìpolongo]." }
{ "en": "Kingsley Moghalu", "yo": "Kingsley Moghalu" }
{ "en": "Moghalu is a professor of international business and public policy at the Fletcher School of Law and Diplomacy at Tufts University in Massachusetts, USA.", "yo": "Moghalu jẹ́ onímọ̀ nínú ìdókòwò àgbáyé àti òfin gbogbo ènìyàn ní ilé ìwé Òfin àti Ọgbọ́n Fletcher ní Ifásitì Tufts ní Massachusetts, USA." }
{ "en": "Moghalu had previously worked in the United Nations from 1992 to 2008.", "yo": "Moghalu ti ṣiṣẹ́ rí ní United Nations láti ọdún 1992 sí 2008." }
{ "en": "He was deputy governor of the Central Bank of Nigeria from 2009 to 2014, where \"he led extensive reforms in the Nigerian banking system after the global financial crisis.\"", "yo": "Ó ti ṣe igbá-kejì gómìnà Ilé Ìfowópamọ́ Àgbà ti Nàìjíríà láti ọdún 2009 sí 2014, níbi tí “ó ti tukọ̀ ọ àwọn àgbà iṣẹ́ àtúnṣe nínú ètò ìkówóoamọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lẹ́yìn ìgbà tí ọrọ̀ Ajé àgbáyé ti ṣe òjòjò tán.”" }
{ "en": "He is the candidate of the Young Progressive Party.", "yo": "Òun ni òǹdíje ní abẹ́ àsíá Ẹgbẹ́ Olóṣèlú Ìtẹ̀síwájú Ọ̀dọ́ – YPP." }
{ "en": "Omoyele Sowore [Screen shot from CNBCAfrica interview, Dec 13, 2018].", "yo": "Ọmọ́yẹlé Sowóre [Àwòrán ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ní orí CNBCAfrica, ní ọjọ́ 13, oṣù Ọ̀pẹ, ọdún 2018]." }
{ "en": "Omoyole Sowore", "yo": "Omoyole Sowore" }
{ "en": "Sowore is the founder and publisher of SaharaReporters (SR), an investigative online newspaper.", "yo": "Sowore ni olùdásílẹ̀ àti atẹ̀wéjáde SaharaReporters (SR), ilé-iṣẹ́ oníròyìn aṣèwádìí orí-ayélujára." }
{ "en": "SR has been described as Africa's Wikileaks.", "yo": "SR ni à ń pè ní Wikileaks Ilé Adúláwọ̀." }
{ "en": "This human rights activist is running under the banner of African Action Congress.", "yo": "Ajà-fún-ẹ̀tọ́-ọmọnìyàn yìí ń jáde lábẹ́ àsíá African Action Congress." }
{ "en": "The race is on for Nigeria's future", "yo": "Aré ti ń lọ fún ọjọ́ iwájú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà" }
{ "en": "Buhari and Abubakar are the major contenders in this race.", "yo": "Buhari àti Abubakar ni afigagbága ìdíje ìbò aré yìí." }
{ "en": "Both men have been constants in the political arena in Nigeria.", "yo": "Àwọn méjèèjì ti ń figagbága nínú ìbò Nàìjíríà ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́." }
{ "en": "On the other hand, Ezekwesili, Moghalu, Sowore, the \"third force\", are a group making their first entry into the partisan political space.", "yo": "Ní ọ̀nà kejì, Ezekwesili, Moghalu, Sowore, àwọn \"agbára ìkẹ́ta\", jẹ́ ẹgbẹ́ tí ó ń wọ inú ètò ìṣèlú fún ìgbà àkọ́kọ́." }
{ "en": "Buhari will be running on the gains of his administration over the past three years and must contend with the fact that Nigeria was recently ranked as the poverty capital of the world.", "yo": "Iṣẹ́ ìṣàkóso Buhari ọdún mẹ́ta ni yóò gbè é lẹ́yìn àti pé yóò bá ìfi Nàìjíríà sí ipò olú orílẹ̀-èdè tí ìṣẹ́ ti pọ̀ jù." }
{ "en": "The Punch newspaper described Buhari’s \"parochial appointments\" as \"unprecedented\" and has left the country deeply divided.", "yo": "Ìwé ìròyìn Punch ṣe ìfojúsùn \"ìpèsípò\" gẹ́gẹ́ bí \"àìròtẹ́lẹ̀ \" àti pé ó ti pín ìlú yẹ́bẹyẹ̀bẹ." }
{ "en": "His fight against corruption appears selective and punitive.", "yo": "Ètò ìgbógunti ìwà àjẹbánu rẹ̀ fì sí ẹ̀gbẹ́ kan." }
{ "en": "The recent move to try the Chief Justice of the Federation — so close to the presidential election — was described by the Nigerian Bar Association as \"a pattern of consistent assault on the heads of the two independent arms of government\" by the Buhari administration.", "yo": "Ìgbésẹ̀ tí ó gbé láì pẹ́ yìí láti ṣe ìgbẹ́jọ́ Adájọ́ Àgbà orílẹ̀ èdè — tí ó ti sún mọ́ ìbò ààrẹ — ni Àjọ Adájọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà Nigerian Bar Association pè ní \"àwòṣe ìkọlù ní lemọ́lemọ́ ní orí àwọn àgbà ẹ̀ka ìjọba méjèèjì tí-kò-gbáralé ìjọba\" ní abẹ́ ìṣàkóso Buhari." }
{ "en": "Abubakar, on the other hand, is riding on the \"gains\" of \"multiple lucrative business interests\".", "yo": "Abubakar, ní ọ̀nà kejì, ń dúró lórí \"ìgbẹ́kẹ̀lé\" àwọn \"ẹgbẹlẹmùkù okòwò tí ó ní èrè lóríi rẹ̀ \"." }
{ "en": "However, he has an uphill task considering the power of incumbency of his major opponent.", "yo": "Bíótiwùkíórí, ó ní láti bá agbára ìwàlóríoyè afigagbága rẹ̀ takọ̀ngbọ̀n." }