_id
stringlengths 17
21
| url
stringlengths 32
377
| title
stringlengths 2
120
| text
stringlengths 100
2.76k
|
---|---|---|---|
20231101.yo_74558_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cgbim%E1%BB%8D%20Apap%E1%BB%8D%20lori%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Ìgbimọ Apapọ lori Àyipada Óju Ọjọ
|
Ìgbimọ Apapọ lori Àyipada Òju ọjọ jẹ ajọ apapọ to da lori pipa àṣẹ lori ayipada óju ọjọ ati ipa rẹ ni órilẹ ede Naijiria.
|
20231101.yo_74558_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cgbim%E1%BB%8D%20Apap%E1%BB%8D%20lori%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Ìgbimọ Apapọ lori Àyipada Óju Ọjọ
|
Ìgbimọ yii ni a da silẹ ni ọdun 2022 labẹ akósó arẹ tẹlẹ ri Muhammadu Buhari lati da ófin kalẹ lori iranlọwọ bi ọrọ ajè ilẹ Naijiria ṣè maa dàgbàsóke.
|
20231101.yo_74558_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cgbim%E1%BB%8D%20Apap%E1%BB%8D%20lori%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Ìgbimọ Apapọ lori Àyipada Óju Ọjọ
|
Àgbèkalẹ ìgbimọ apapọ lori ayipada óju ọjọ kari óriṣiriṣi ẹka ati ọfiisi alakósó. Awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ naa:
|
20231101.yo_74558_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cgbim%E1%BB%8D%20Apap%E1%BB%8D%20lori%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Ìgbimọ Apapọ lori Àyipada Óju Ọjọ
|
Awọn ọmọ ẹgbẹ to ku ni Awọn minisita fun Ayikà, ọrọ ọmi, ọrọ ina, gbigbè, Àgbẹ ati Idagbasókè igbèriko, ọrọ óbirin ati Idagbasókè Awujọ, Ọrọ ówó, Íṣuna ati ọrọ ètó apapọ, amofin gbogboogbo ilẹ Naijiria ati Minisita lori Ìdajọ.
|
20231101.yo_74559_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Deoband
|
Deoband
|
Deoband jẹ́ ìlú kan tí ó ní ìjọba ìbílẹ̀ tirẹ̀ ní agbègbè Saharanpur ní ìpínlẹ̀ Uttar Pradesh, India, nípa bíi 150 km láti Delhi. Darul Uloom Deoband, ilé-ẹ̀kọ́ Islam àti ọ̀kan nínú àwọn ilé-ẹ̀kọ́ Islam tí ó tóbi jùlọ ti India wà níbẹ̀.
|
20231101.yo_74560_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Deobandi%20Movement
|
Deobandi Movement
|
Ẹgbẹ́ Deobandi tàbí Deobandism jẹ́ ẹgbẹ́ ìsọjí láàárín Sunni Islam tí ó faramọ́ ilé-ìwé òfin Hanafi. Ó ṣẹ̀dá ní ìparí ọ̀rúndún ọ̀kàn-dín-lọ́gún ní àyíká Madrassa Darul Uloom ní Deoband, India, láti èyítí orúkọ náà ti gbà, , nípasẹ̀ Muhammad Qasim Nanautavi, Rashid Ahmad Gangohi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn, lẹ́hìn Ìsọ̀tẹ̀ India ti 1857 sí 58. Wọ́n ka ara wọn sí ìtèsíwájú Ahlus Sunnah wal Jamaat. Ìdí pàtàkì ẹgbẹ́ yìí ni láti kọ́ ìjọsìn tipátipá, shirk àti ìdáàbòbò ìlànà ẹ̀sìn Islam lọ́wọ́ Bidah, àti ipa àwọn àṣà tí kìí ṣe Mùsùlùmí lórí Mùsùlùmí ti South Asia.
|
20231101.yo_74562_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/J.%20J.%20Abrams
|
J. J. Abrams
|
Jeffrey Jacob Abrams (a bíi ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà, ọdún 1966) jẹ oṣere ati olupilẹṣẹ ara ilu Amẹrika kan. O jẹ olokiki julọ fun awọn iṣẹ rẹ ni awọn oriṣi iṣe, eré, ati itan-akọọlẹ imọ-jinlẹ. action, drama, àti science fiction. Abrams kọ̀wé ó sì ṣe àgbéjáde irú àwọn fíìmù bíi Regarding Henry (1991), Forever Young (1992), Armageddon (1998), Cloverfield (2008), Star Trek (2009), Star Wars: The Force Awakens (2015), àti Star Wars: The Rise of Skywalker (2019).
|
20231101.yo_74562_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/J.%20J.%20Abrams
|
J. J. Abrams
|
Abrams ti ṣẹda ọpọlọpọ àwọn tẹlifiṣàn síríísì, pẹ̀lú Felicity (olupilẹṣẹ, 1998–2002), Alias (olùṣẹ̀dá, 2001–2006), Lost (olupilẹṣẹ, 2004–2010), and Fringe (olùpilẹ̀ṣẹ̀, 2008–2013). Ó gba àwọn ẹ̀bùnEmmy àwọ́ọ̀dù méjì fún Lost – Outstanding Directing for a Drama Series àti àwọn járá Eré tí ó tayọ.
|
20231101.yo_74562_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/J.%20J.%20Abrams
|
J. J. Abrams
|
Iṣẹ́ dídarí fíìmù rẹ̀ pẹ̀lú Mission: Impossible III (2006), Star Trek (2009), Super 8 (2011), àti Star Trek Into Darkness (2013). Ó tún ṣe itọsọna, ṣe agbejade ati ṣajọpọ The Force Awakens, ti ìran ẹlẹ́ẹ̀keje ti Star Wars saga àti fíìmù a lákọ̀ọ́kọ́ ti sequel trilogy náà. Fíìmù náà jẹ́ olówó lórí tí ó ga jùlọ, bákannáà ni ẹlẹ́karùn-ún fíìmù tí ó lówó lórí jùlọ tí gbogbo ìgbà tí ò sún kúrò ní ẹ̀léwó. Ó padà sí Star Wars Pẹ̀lú ipò alákòóso The Last Jedi (2017), àti adarí alájọkọ The Rise of Skywalker (2019).
|
20231101.yo_74562_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/J.%20J.%20Abrams
|
J. J. Abrams
|
Àwọn alabaṣiṣẹpọ ìgbà gbogbo Abrams pẹ̀lú olùpilẹ̀ṣẹ̀ Bryan Burk, Alákòós/Olùdarí Damon Lindelof àti Tommy Gormley, àwọn òṣèré Greg Grunberg, Simon Pegg, Amanda Foreman, àti Keri Russell, kọ̀m̀pósà Michael Giacchino, àwọn òǹkọ̀we Alex Kurtzman àti Roberto Orci, cinematographers Daniel Mindel àti Larry Fong, àti àwọn aṣe-fọ́nrán-eré-lọ́jọ́ Maryann Brandon àti Mary Jo Markey.
|
20231101.yo_74563_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Asghar%20Hussain%20Deobandi
|
Asghar Hussain Deobandi
|
Asghar Hussain Deobandi (ti atun lè pé ní Mian Sayyid Asghar Hussain) (16 October 1877 — 8 January 1945) je akeko gboyè ni imọ Mùsùlùmí Indian Sunni ó pelu awon oludasile Madrasatul Islah.
|
20231101.yo_74563_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Asghar%20Hussain%20Deobandi
|
Asghar Hussain Deobandi
|
Àbí ni ojo kẹrin dín lógún ọsu Kẹ̀wá ọdún 1877 sì ìdí ilé Deoband, ojewo olóòótọ́ ènìyàn siAbdul Qadir Jeelani, Asghar Hussain Deobandi je akeeko gboyè ni Darul Uloom Deoband, níbi ti ó keko pẹlu Mahmud Hasan Deobandi, Azizur Rahman Usmani ati Hafiz Muhammad Ahmad. Hussain Je ọmọlẹ́yìn fun Imdadullah Muhajir Makki ninu Chishti Sufi order. Oko àwọn akeko nípa imo ìjìnlè sayensi nínú ẹṣin níí Atala Masjid, Jaunpur àti ní ibi ti ó ti ké kò gboye, Darul Uloom Deoband. Ó pẹ̀lú àwọn tó ṣe afi kún sí ìwé Oso oṣù tí àwọn ' Darul Uloom Deoband ma ń tẹ jade.' ti a pé ní Al-Qasim, Hussain je ìpè Ọlọ́run ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kini odun1945 ni Surat, wọn si sìn sí Rander. Àwọn akeko ni wonyiManazir Ahsan Gilani ati Muhammad Shafi Deobandi.
|
20231101.yo_74563_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Asghar%20Hussain%20Deobandi
|
Asghar Hussain Deobandi
|
Àwọn babanla Mian Asghar Hussain's wá sí ìlú India láti ilu Baghdad won wa si ọ̀nà ìsàlè latiAbdul Qadir Jeelani. ní igbà ayé àwọn Shah Jahan, Sayyid Ghulam Rasool tí losi ìlú India ohùn àti àwọn ẹbí rẹ. wọn yonda imamat àti khitabat fún ní ibì Shahi Masjid tí Deoband. Oni ọmọkùnrin meji, Ghulam Nabi àti Ghulam Ali. Àwọn ọkùnrin méjèèjì fẹ́ ọmọ obìnrin tí Shah Ameerullah.
|
20231101.yo_74563_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Asghar%20Hussain%20Deobandi
|
Asghar Hussain Deobandi
|
Sayyid Ghulam Ali ni ọmọ obìnrin mẹta àti ọkùnrin méjì. Èyí tí ó dàgbà jù tí orúkọ rẹ njẹ Alam Meer ni bàbá bàbá Mian Asghar Hussain. Alam Meer fe Azeemun Nisa, ọmọbìnrin tì Shah Hafeezullah. Wọn ní ọmọ obìnrin tí orúkọ rẹ̀ njẹ Wajeeh-un-Nisa àti ọmọkùnrin tí orúkọ rẹ nje Muhammad Hasan, ó jé bàbà fún Mian Asghar Hussain. Muhammad Hasan fe ìyàwó ni ẹ méjì, àkókò o fe Maryam-un-Nisa, tí ó bí ọmọkùnrin kan funti orúkọ rẹ nje Sayyid Khursheed, àti ọmọbìnrin kan tí orúkọ rẹ njẹ Masum-un-Nisa. Lẹ́yìn ikuAfter Maryam-un-Nisa's, Muhammad Hasan fẹ́ àbúrò rè tó ń jẹ Naseeb-un-Nisa; won ni omokunrin kàn, Asghar Hussain.
|
20231101.yo_74563_4
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Asghar%20Hussain%20Deobandi
|
Asghar Hussain Deobandi
|
Àbí Mian Asghar Hussain ni ọjọ́ kẹrin dín lógún oṣù Kẹ̀wá odun 1877 ni ilu Deoband sì ìdílé Sayyid Muhammad Hasan ati Naseebun Nisa bint Sayyid Mansub Ali.
|
20231101.yo_74563_5
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Asghar%20Hussain%20Deobandi
|
Asghar Hussain Deobandi
|
Orúkọ Mùsùlùmí re ni ism (given name) Asghar Hussain. Tire nasab (patronymic) is: Sayyid Asghar Hussain ibn Sayyid Shah Muhammad Hasan ibn Sayyid Shah Alam Meer ibn Sayyid Ghulam Ali ibn Sayyid Ghulam Rasool Baghdadi ibn Sayyid Shah Faqeerullah Baghdadi ibn Sayyid A’zam Saani ibn Sayyid Nazar Muhammad ibn Sayyid Sultan Muhammad ibn Sayyid A’zam Muhammad ibn Sayyid Abu Muhammad ibn Sayyid Qutbuddin ibn Sayyid Baha’uddeen ibn Sayyid Jamalauddin ibn Sayyid Qutbuddin ibn Sayyid Dawud ibn Muhi’uddin Abu Abdullah ibn Sayyid Abu Saleh Nasr ibn Sayyid Abdur Razzaq ibn Abdul Qadir Jilani.
|
20231101.yo_74563_6
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Asghar%20Hussain%20Deobandi
|
Asghar Hussain Deobandi
|
Ní ọmọ ọdún mẹ́jọ, ó ń kẹ́ko pẹ̀lú Muhammad Abdullah, alias Miyanji Munne Shah osi ko eko Quran láti owó bàbà ẹ ọ̀tẹ̀ síwájú láti kó ni pá Persia lowo bàbà e. Wọn padà gba wọlé sí Ìle ekoDarul Uloom Deoband. Ọ̀tẹ̀ síwájú pelu kíláàsì Persia ọkọ Persian lowo Muhammad Yaseen, bàbàa Muhammad Shafi Deobandi. Oko eko imo ìsirò ni Manzoor Ahmad. Òye gé ìyára ikawe persiani pelu ipò ikini o gbaa ẹ̀bùn Muwatta Imam Malik gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn idanilola . Bí Asghar Hussain ṣe pé ọmọ ọdún mẹta dín lógún sì méjì dín lógún tio de ìyára ikawe arabic ni Darul Uloom Deoband, bàbà rẹ jáde láyé ni ogún jọ oṣù Kẹ̀sán odun 1894. Ó dá ẹnu dúró nínú èkó rè fún bí ọdún kan ó tesiwaju láti kó àwọn ọmọ lè kó ni ọdọ àwọn bába ńlá e madrasa.
|
20231101.yo_74563_7
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Asghar%20Hussain%20Deobandi
|
Asghar Hussain Deobandi
|
Ní ìbéèrè awon Mahmud Hasan Deobandi, Asghar Hussain wo ile eko Darul Uloom Deoband lekan sì ni ojo kini oṣù kẹrin odun 1896 oṣù tesiwaju nínú ìyára ikeko arabic. Oko nípa Sahih al-Bukhari, Sahih Muslim, Jami` at-Tirmidhi atiSunan Abu Dawood pelu Mahmud Hasan Deobandi. Àwọn olùkọ́ rẹ tó ni Azizur Rahman Usmani ati Ghulam Rasool Baghwi. Oko eko gboyè ní 1320 AH osi gba àmì ikeko gboyè ni owo Mahmud Hasan Deobandi ati Hafiz Muhammad Ahmad.
|
20231101.yo_74563_8
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Asghar%20Hussain%20Deobandi
|
Asghar Hussain Deobandi
|
Leyin eko rẹ ni Darul Uloom Deoband, òsì ṣe gege bí òṣìṣẹ́ ní Darul Uloom kò já ọdún kan. Àwọn olùkọ́ re Mahmud Hasan Deobandi àti Hafiz Muhammad Ahmad rán lọ si madrassa tí Atala Masjid, Jaunpur fún ipò oluko àgbà òsì sise fún ọdún meje. Ní àwọn àkókò ni ọdún 1327 AH, òfin òkúta ilé Madrasatul Islah lè ilé ni Sarai Meer, Azamgarh ni 1908.àpe si Darul Uloom Deoband asi fun ni ipo alatunse pelu awon tó ń ṣe atun ṣe sí journal Al-Qasim ti Darul Uloom, tí alatunse na si je Maulana Habeebur Rahman. Afun ni ipò oluko ti Sunan Abu Dawud ni Darul Uloom Deoband otun kò àwọn akeko ni ìwé tafsir àti fiqh like Jalalayn ati Durr-e-Mukhtar. His notable students include Muhammad Shafi Deobandi, Manazir Ahsan Gilani. and Mufti Naseem Ahmad Fareedi. Otun madrasa àwọn bàbà ńlá rẹ ṣe tí àti parí láti ìgbà ikú bàbà re. madrasa padà wá lábé akoso ọmọ kunrin rẹ Sayyid Bilal Hussain Mian (d. 9 February 1990) orúkọ rẹ láwàní pé ni Madrassa Asgharia Qadeem tí orúkọ ìtàn rẹ njẹ Darul Musafireen, Madrasa Taleemul Quran.
|
20231101.yo_74563_9
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Asghar%20Hussain%20Deobandi
|
Asghar Hussain Deobandi
|
Ní ìgbà ikeeko rẹ ni Darul Uloom Deoband, Hussain fe ọmọbìnrin ti Mushtaq Hussain. Wọn ní ọmọkùnrin meji, tí ń ṣe Sayyid Akhtar Hussain ati Mian Bilal Hussain, àti ọmọ obìnrin kan, Fehmeeda. Fehmeeda òkú lẹ́yìn ọdún mejo tí ó ṣe ìgbéyàwó, ọmọ rẹ ọkùnrin sì gbeyin rẹ Syed Farhat Hussain tí òní àjò sepo pelu Hamdard Dawakhana ni Karachi. ọmọkùnrin Hussain's tí njẹ Sayyid Akhtar Hussain je olùkọ́ hadith ni Darul Uloom Deoband, ósìn ni ọ́fíìsì seminari. Hussain's ati awon ọmọkùnrin èmi Sayyid Bilal Hussain omokunrin meta tí ńṣe , Sayyid Jameel Hussain, Sayyid Khaleel Hussain, and Sayyid Jaleel Hussain sì gbeyin won; ati ọmọbìnrin méjì tí nse, Sajida Khatun ati Aabida Khatun.
|
20231101.yo_74563_10
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Asghar%20Hussain%20Deobandi
|
Asghar Hussain Deobandi
|
Àìsàn ọkàn pá Mian Asghar Hussain ni ojo kẹjọ oṣù kini ọdún 1945 (22 Muharram 1364 AH).won si sin si Rander, Surat.
|
20231101.yo_74564_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8C%E1%B9%A3il%E1%BB%8D%20ati%20%C3%80yipada%20lori%20%C3%80yika%20%C3%81gb%C3%A0y%C3%A8
|
Ìṣilọ ati Àyipada lori Àyika Ágbàyè
|
Ìṣilọ ati Àyipada lori Àyika Ágbàyè jẹ Ìwadi nipa ipa ti ayipada óju ọjọ kó ninu ìṣilọ ọmọ èniyan ati iṣikuró ni wọn tẹ si ta ni ọdun 2011. Iwadi yii wa lati ẹka èró ni àbẹ àkósó ijọba UK to da lori imọ ijinlẹ̀.
|
20231101.yo_74564_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8C%E1%B9%A3il%E1%BB%8D%20ati%20%C3%80yipada%20lori%20%C3%80yika%20%C3%81gb%C3%A0y%C3%A8
|
Ìṣilọ ati Àyipada lori Àyika Ágbàyè
|
Eyi ni wọn pe ni èró Iroyin larin awọn ti oun ṣiṣẹ ni abẹ ójù ọjọ ati ìṣilọ. Iroyin ni Ọjọgbọn Richard Black ti ilè iwè giga Sussex ṣaju rẹ. Ìwadi fi ọwọ si àyọka lori ìṣilọ ati ayipàdà òjù ọjọ. Iwadi yii fi igbèroyin jade lori gbigbè jadè rẹ.
|
20231101.yo_74564_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8C%E1%B9%A3il%E1%BB%8D%20ati%20%C3%80yipada%20lori%20%C3%80yika%20%C3%81gb%C3%A0y%C3%A8
|
Ìṣilọ ati Àyipada lori Àyika Ágbàyè
|
Iwadi yi da lori èró ti wón dè mọlẹ. Iroyin sọpè latara ayipada ójù ọjọ awọn èniyan ni lati duró sibi ti wọn wa. Iwadi fi idi ẹ mọlẹ pe eyi jẹ̀ ki awọn èniyan di tàlàkà latari ìbajẹ ilẹ̀. Iroyin yii jẹ ko gbajumọ pè iṣilọ ni aṣamubadọgba fun ayipada ójù ọjọ. Awọn ólukọwè litirèsọ sọpe ìṣilọ jẹ ọna kan gbogi ti awọn èniyan maa farada ipa ti ayipada òju ọjọ kó ni ìṣilọ.
|
20231101.yo_74567_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Akah%20Nnani
|
Akah Nnani
|
Akah Nnani jẹ́ òṣèrékùnrin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, olóòtú èò lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán, àti òṣìṣẹ́ orí YouTube. Ó gbajúmọ̀ fún ìkópa rẹ̀ nínú fíìmù àgbéléwò Banana Island Ghost, èyí tó mu kí wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá àti ìkẹẹ̀ẹ́dógún ti The AMA Awards fún òṣèrékùnrin tó dára jù, ní ọdún 2018 àti 2019. NÍ ọdún 2022, ó kópa nínú fíìmù Netflix kan, tí àkọ́lé rè ń jẹ́ Man of God, ẹ̀dá-ìtàn tó sì ṣe ni Samuel Obalolu.
|
20231101.yo_74567_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Akah%20Nnani
|
Akah Nnani
|
Akah Nnani wá láti Ipinle Imo, wọ́n sì bi ní January 31, ní Port Harcourt, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pẹ̀lú àbúrò mẹ́ta. Bàbá rẹ̀ jẹ́ oṣiṣẹ́ ní Immigration office, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ oníṣòwò. Ó lọ sí ilé-ìwé Pampers Private School, ní Surulere, fún ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, ilé-ìwé Topgrade Secondary School ló sì ti kọ́ ẹ̀kọ́ girama, ní Surulere. Ó gboyè B.Sc. nínú ẹ̀kọ́ Mass Communication láti Covenant University.
|
20231101.yo_74569_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba tí ìnagijẹ rẹ̀ ńjẹ́ Mohbad tàbí Ìmọ́lẹ̀ ( wọ́n bíi ní 8 June, 1996 ó dágbére fáyé ní 12 september 2023), jẹ́ akọrin tàkasufe ati onkọrin tí oún gbé ní ìlú èko. ó kọ́ n gbé orin síta pẹ̀lu àtìlẹ́hin ilé iṣẹ́ ìgb'órin síta ti Naira Marley (Marlian Records), ó kúrò ní abẹ́ ilé iṣẹ́ yí ní ọdún 2022. ó gbajúgbajà pẹ̀lú àwọn orin àdákọ rẹ̀ bíi "Ponmo", "Feel Good" àti "KPK (Ko Pọ kẹ) tí ó gba ìtọ́kasí ẹ́mẹ́ta fún àmì ẹ̀yẹ (The Headies awards) ni ọdún 2022.
|
20231101.yo_74569_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Mohbad gbé àwo orin àkọ́kọ́ rẹ̀ tí ó pe àkọlé rẹ̀ ni "Light" (Ìmọ́lẹ̀),jade nínú ọdun 2020, eleyi ni o tẹ̀le orin "Ponmo", tí ó ti ṣe papọ̀ pẹ̀lu Naira Marley àti Lil Kesh. Mohbad gba itọkasi ẹmarun fún àmì ẹ̀yẹ (The Beatz Awards) ní ọdún 2021.
|
20231101.yo_74569_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
wọ́ ka Mohbad kún àwọn olorin mọkanlelogun akọ́kọ́ (top 21) lori àtẹ Audiomack ní ọdun 2021. Ni ọdún 2022, Mohbad tún ṣe orin tuntun míràn láti ọwọ Rexxie tí ó pè ni "peace". Ó leke tente tabili aadota (50) orin TurnTable charts ní ọdún 2021 àti ọgọrun (100) àkọ́kọ́ ni ọdún 2022. Orin "peace kanna tún gbégba oróke lórí atẹ Apple Music Chart Nigeria.
|
20231101.yo_74569_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Mohbad darapọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ orin "Marlian Records World" ni ọdún 2019 níbi ti ó ti gbé orin "light" jade orin yí jẹ́ ipele mẹ́jọ, Davido, Naira Marley ati Lilkesh kópa pẹ̀lu rẹ̀.
|
20231101.yo_74569_4
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Naira Marley ni alakoso àwo orin naa pẹ̀lu àjọsepọ ilé iṣẹ́ "SB, Rexxie, P.Beat ati Austin Sinister.
|
20231101.yo_74569_5
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Àwo orin "Blessed" ní ó kọ́ ṣe ní June 2023, lẹ́hin tí o kúro lábẹ ilé iṣẹ́ Marlian Records tí o ṣẹda ilé iṣẹ́ orin tirẹ̀ tí ó pè ni "Imolenization". Blessed jẹ́ àkójọpọ̀ orin ọtọtọ mẹjó tí wọ́n gba ogun-isẹju lapapo. lara wọn ni o ti kopa pẹlu Zlatan àti Bella Shmurda, labẹ ìsàkóso Niphkeys ati Timi Jay. Àwo naa gbégbá orókè lori àtẹ Apple Music ni Nigeria ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tí o jade, àti ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tí Mohbad jade laye.
|
20231101.yo_74569_6
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Ní Februari 2022, àjọ tí o gbógun ti lílo egbogi olóró (NDLEA) fi òfin gbé Mohbad, Zinoleesky àti àwọn mẹ́rin míràn ní ilé wọn tí o wà ní Lekki, ìpínlẹ̀ Èko fún níní egbò igi oloro bíi MDMA àti igbó (cannabis) ni'kawọ.
|
20231101.yo_74569_7
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Àwọn fọọnran kan lórí ẹ̀ro ayélujara ṣe àfihàn bí àwọn òṣiṣẹ àjọ tí o gbógun ti lílo egbogi olóró (NDLEA) ṣe wọ inú ilé àwọn olorin naa tí ó wà ní agbègbè Lekki ní ìpinlẹ̀ Eko. Gẹ́gẹ́bí wọn ṣe sọ, àwọn òṣiṣẹ àjọ tí o gbógun ti lílo egbogi olóró (NDLEA) fi ofin mú àwọn olorin naa lai ní ìwé asẹ ifofin múni tí wón si fi ìyà tí ó lówúra jẹwọ́n.
|
20231101.yo_74569_8
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Àjọ tí o gbógun ti lílo egbogi olóró (NDLEA) jẹri si ìréde na lati ẹnu agbẹnusọ wọn wipe lootọ ni wọn ba egbò igi oloro bíi MDMA àti igbó (cannabis) ni'kawọ wọn. Léhin-o-rẹhin wọn da Mohbad, Zinoleesky àti awọn mẹ́rin yooku sílẹ̀.
|
20231101.yo_74569_9
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Léyìn tí Mohbad ti lo ọdun meji pẹlu ilé iṣẹ́ Marlian Records ni ó kéde iyapa ati yíyan alakoso tuntun fun isẹ́ orin re. Ní ọjọ́ karun (5) October 2022, Mohbad fi ẹ̀sùn kan Naira Marley (òga rẹ nigbakan) pe oun dúnkokò mọ́ òun o si n ran àwọn kan láti maa na oun káàkiri.
|
20231101.yo_74569_10
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Lẹ́yìn iku Mohbad ni ó hàn síta wipe saaju ni o ti kọwe sí àjọ ọlọpa ni June 2023, nínú èyí tí ó ti fi ẹ̀sùn kan Samson Erinfolami Balogun (Sam Larry) ọrẹ Naira Marley, tí o jé olu-gbe-orin larugẹ wípé o fi ìyà jẹ òun l'ónà àìtọ́ ó si tún ba dúkìá òun jẹ́. O tún tẹ̀síwájú nínú iwé náà wipe Sam Larry ko àwọn ọkunrin marundogun lẹyin wa pẹ̀lu àwọn ohun ìjà bi ibọn àti àdá ní ọwọ wọ́n wá sí ibi tí oun ti n ṣe iyaworan orin tí wọn si wípé wọn ṣiṣẹ fún Oba Elegushi. Àjọ Ọlọpa sọ wípé Mohbad ko pada yọjú sí àgọ́ wón lẹyìn tí wọn fí iwe pe lati wa fun ijiroro lori iwe ẹsun tí o kọ, àti wípé Sam Larry àti àwọn míràn tí ó fi ẹsùn kan ti kọ ìwé ìbanilórúkọjẹ́.
|
20231101.yo_74569_11
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Ọba Ẹlẹgushi ṣe atẹjade lòdì sí ìbásepọ́ pẹ̀lu Samson Erinfolami Balogun (Sam Larry), o sì ránṣẹ́ ìbánikẹ́dun nípa iku Ilerioluwa Oladimeji Alọba (Mohbad).
|
20231101.yo_74569_12
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Mohbad ni ọmọkunrin kan pẹ̀lu aya rẹ Omowunmi, tí wọ́n bi ni April 2023. Mohbad kú lẹ́yìn tí o lọ gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn ni 12 September, 2023 ní ọmọ ọdún mẹtadinlọgbọn (27). Àjọ ọlọpa kéde láti ṣe iwadi irú ikú tí o pa olorin naa lẹ́yìn tí wọ́n wu oku rẹ sita ni 21 September, 2023.
|
20231101.yo_74569_13
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Ni ojo 21 Oou Kosan, odun 2023, Niran Adedokun kowe ninu Iwe iroyin Punch pe Mohbad "jo abinibi pupo ati ni ibamu polu omi orin gan-an".
|
20231101.yo_74569_14
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ilerioluwa%20Oladimeji%20Aloba%20%28Mohbad%29
|
Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
|
Nigba oniwaasu Naijiria ati buloogi ti o da ni Warri, Isaiah Ogedegbe, ti o apejuwe ro Mohbad bi "okan ninu awon akorin nla julo ni gbogbo agbaye".
|
20231101.yo_74570_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Aarun%20%C3%93mi%20ati%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Aarun Ómi ati Àyipada Óju Ọjọ
|
Àyipada Óju Ọjọ lo ti fa óriṣiriṣi itankalẹ ààrun ati ailèra papa èyi to farapẹ ti ómi. Ìpa Àyipada óju ọjọ lo ti wa kakiri àgbàye ninu ọgbẹlẹ, ikun ómi, ójó rirọ to lagbàrà ati ómi to lọwọrọ. Eyi lo fa aàrun omi to si tu bọ pọsi kakiri ààgbàyè. Àlèkun ótutu ati iyipada ninu ójó mu ki ààrun ómi jẹ ọkan gbogbi ninu ipa ètó ilèra to wa latara àyipada óju ọjọ.
|
20231101.yo_74570_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Aarun%20%C3%93mi%20ati%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Aarun Ómi ati Àyipada Óju Ọjọ
|
Ààrun ómi jẹ awọn aisan to wa lati ara koko ti àkolè fójuri to wa ninu ómi. Àmi aisan naa ni ìgbè gbùrù, ìba, àilera ati bibajẹ ẹdọ.
|
20231101.yo_74570_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Aarun%20%C3%93mi%20ati%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Aarun Ómi ati Àyipada Óju Ọjọ
|
Àyipada óju ọjọ ti ko ipa ninu itankalẹ awọn kokoro aifojuri yi, ọkanlara awọn aisan naa ni àisan ìgbẹ gbùrù to wa latari mimu omi ti ko da tabi lilo wọn eyi lo si ti fa iku aimoyè awọn ọmọọdè. Aisan ìgbẹgbùrù ti ṣè ókunfa iku awọn èniyan millionu 1.4-1.9 lagbàyè. Gẹgẹbi ajọ ijọba to da lóri igbẹ̀jọ ti ayipada ójù ọjọ eyi ti ólóyinbo mọsi "Intergovernmental Panel on Climate Change (IPCC)", Àlèkun ti ba itankalẹ ààrun omi latara ayipada óju ọjọ.
|
20231101.yo_74570_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Aarun%20%C3%93mi%20ati%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Aarun Ómi ati Àyipada Óju Ọjọ
|
Iwọn ààlèkun óóru fa alèkun kokoro aifojuri ninu ara awọn èrankó ati ninu ómi mimu. Nigba óóru, omi mimu jẹ̀ àlèkun eyi lo maa fa itankalẹ awọn kokoro aifojuri ti oun fa ààrun ómi bi igbẹ gbùrù. Ni àgbègbè to gbóna papa èyi to ni ómi kèkèrè alèkun wa ninu ómi ti wọn gba ti wọn si tun ló pada. Eyi le fa alekùn ninu ómi ti o ti dọti.
|
20231101.yo_74570_4
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Aarun%20%C3%93mi%20ati%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Aarun Ómi ati Àyipada Óju Ọjọ
|
Ayipada ójù ọjọ ti fa alekùn ba ójó rirọ eyi lo fa aimoye ikùn ómi. Iwadi sọpè ààrun igbẹ gbùrù ati ikun jẹ ọkan lara ipà ọjọ. Latara ójó to pọ lo fa alèkun ba kokoro aifójuri to si ko iparun ba imọtótó ati ómi àgbègbè naa.
|
20231101.yo_74570_5
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Aarun%20%C3%93mi%20ati%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Aarun Ómi ati Àyipada Óju Ọjọ
|
Ikun ómi ko ipa lori ètó ilèra, kokoro aifojuri to wa lati igbọsẹ awọn eniyan tabi èrankó to wa ni inu ilẹ ko iparun ba ómi ilẹ to si maa nkóba awọn èniyan to ba mu iru ómi naa.Ójó to ba lagbara maa da ómi ódó pọ mọ omi to wa lati ṣalanga to si jẹ akoba fun omi mimu to wa lati ilẹ.
|
20231101.yo_74570_6
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Aarun%20%C3%93mi%20ati%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Aarun Ómi ati Àyipada Óju Ọjọ
|
Ikun ómi jẹ ọkan lara ókunfa àlèkun to ba ààrun omi papa ni órilẹ ede to ti dagba sókè ni awọn àgbègbè ti akoba ti ba ómi mimù wọn.
|
20231101.yo_74570_7
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Aarun%20%C3%93mi%20ati%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Aarun Ómi ati Àyipada Óju Ọjọ
|
Ójó ni awọn àgbègbè kan lo ti fa ọgbẹlẹ̀ si agbègbè ti ójó ko rọ. Eyi lo fa èkun ba awọn idọti inu omi kiwọn kuró, eyi lo mu ki kokoro aifojuri dojukọ iwọn ba ómi to wa ni agbègbè naa.
|
20231101.yo_74570_8
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Aarun%20%C3%93mi%20ati%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Aarun Ómi ati Àyipada Óju Ọjọ
|
Ọgbẹlẹ tun maa njẹ ki awọn èniyan gbẹkẹlè ómi ojo ati ómì èti ọna eyi lo maa fa akóba latara kokoro aifojuri to maa nfa ààrun ómi.
|
20231101.yo_74572_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ip%C3%A0%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%20ninu%20%E1%BA%B8k%E1%BB%8D%20%E1%BB%8Cgbin
|
Ipà Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin
|
Ìpa Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin ti jasi èrè ókó kèkèrè ati onjẹ iyè nitori ọgbẹlẹ, óoru igbi ati ìkun ómi eyi lo fa alèkun ba ajẹnirun ati ààrun ohun ọgbin.
|
20231101.yo_74572_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ip%C3%A0%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%20ninu%20%E1%BA%B8k%E1%BB%8D%20%E1%BB%8Cgbin
|
Ipà Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin
|
Ayipada ninu óju ọjọ ko ipa ninu àgbègbè fun iṣẹ àgbẹ. Óóru maa njẹ adikun fun ìkórè ọgbin ni gbógbó àgbègbè bi ilẹ Canada ati àpà Ariwa ilẹ U.S. Ọpọlọpọ oun ọgbin lo maa nbajẹ nitori óóru.
|
20231101.yo_74572_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ip%C3%A0%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%20ninu%20%E1%BA%B8k%E1%BB%8D%20%E1%BB%8Cgbin
|
Ipà Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin
|
Ni ọdun 2018, óóru nitori àyipada ójù ọjọ fa adinku ba ìkórè ọgbin papa julọ ilẹ Europe. Ni óṣù August, ọpọlọpọ óun ọgbin lo bajẹ eyi lo fa ọwọn ounjẹ ni àgbàyè.
|
20231101.yo_74572_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ip%C3%A0%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%20ninu%20%E1%BA%B8k%E1%BB%8D%20%E1%BB%8Cgbin
|
Ipà Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin
|
Ọgbẹlẹ ati ìkun omi maa jasi adinku ìkórè ọgbin eyi lo ma jasi iparun ọgbin ati ounjẹ. Ọgbẹlẹ ni awọn ilu to dàgbàsókè maa nfa iyan ati àìjẹunrekánú.
|
20231101.yo_74572_4
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ip%C3%A0%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%20ninu%20%E1%BA%B8k%E1%BB%8D%20%E1%BB%8Cgbin
|
Ipà Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin
|
Fifi ómi si nkan ọgbin dinku eyi lo ma fa adinku ba ìkórè ọgbin. Nitori airi ójó, atiri ómi fun nkan ọgbin jẹ inira nitori pe latari ọgbẹlẹ ọpọlọpọ ódó lo maa ngbẹ eyi lo mu wiwa ómi lọsi ibómiran.
|
20231101.yo_74572_5
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ip%C3%A0%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%20ninu%20%E1%BA%B8k%E1%BB%8D%20%E1%BB%8Cgbin
|
Ipà Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin
|
Nitóri afikun aropin iwọn gbigbona tabi otutu, ọgbẹ̀lẹ wọpọ ni ilẹ Africa, Australia, gùùsù Europe ati Asia. Ìpa naa pọ nitori aini omi ati idàgbàsókè ilú. Ọgbẹlẹ jẹ́ akoba fun óun ọgbin ati nkan ọsin. Awọn àgbẹ maa nkuró ni àgbègbè kan lọ si ibó miran nitori ọgbẹlẹ.
|
20231101.yo_74572_6
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ip%C3%A0%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%20ninu%20%E1%BA%B8k%E1%BB%8D%20%E1%BB%8Cgbin
|
Ipà Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin
|
Àfikun aropin iwọn gbigbona tabi otutu ko ipa ninu àjẹnirun, ààrun ọgbin ati korikó eyi lo fa adinkun ba ìkórè ọgbin.
|
20231101.yo_74572_7
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ip%C3%A0%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%20ninu%20%E1%BA%B8k%E1%BB%8D%20%E1%BB%8Cgbin
|
Ipà Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin
|
Kókóró aifójuri ti ko pa ninu èrè ókó àgbàyè, ipèlè yi lè fa alèku ba óun ọgbin ati idàgbàsókè awọn àjẹnirun. Ìgbà óóru maa fa àlèkun ba idàgbàsókè ba kókóró inu ókó. Awọn ẹya kókóró yii ni wọn tete maa nbimọ nitori ayipada òjù ọjọ.
|
20231101.yo_74572_8
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ip%C3%A0%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%20ninu%20%E1%BA%B8k%E1%BB%8D%20%E1%BB%8Cgbin
|
Ipà Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin
|
Ìkun ómi tabi ójó to lagbara maa nfa àlèkun ba idagbasókè awọn ajẹnirun ọgbin ati ààrun. Ọgbẹlẹ ni apa kan maa nfa idagbasókè óriṣiriṣi àjẹnirun bi kokoró aphid, ẹfọn funfun ati èsù.
|
20231101.yo_74572_9
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ip%C3%A0%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%20ninu%20%E1%BA%B8k%E1%BB%8D%20%E1%BB%8Cgbin
|
Ipà Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin
|
Ayipada ójù ọjọ le jasi óóru eyi lo ma fa ki èsù bó awọn ókó nibi ti wọn ti ma ba oun ọgbin jẹ. Eyi ti ṣẹlẹ ni órilẹ èdè ìla óórun Afrika ni ibẹrẹ ọdun 2020.
|
20231101.yo_74572_10
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ip%C3%A0%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%20ninu%20%E1%BA%B8k%E1%BB%8D%20%E1%BB%8Cgbin
|
Ipà Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin
|
Ni ọdun 2007, Iwọn àyipada óju ọjọ ṣè àlèkun ba óun ọgbin latari ójó ṣugbọn gbẹkèlè óriṣiriṣi àgbègbè. Àkànṣè Ètó sọpè eyi lè dinku èbi lagbayè ni ọdun 2080 pẹlu afiwè ipèlè ọdun 2006.
|
20231101.yo_74572_11
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ip%C3%A0%20%C3%80yipada%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D%20ninu%20%E1%BA%B8k%E1%BB%8D%20%E1%BB%8Cgbin
|
Ipà Àyipada Óju Ọjọ ninu Ẹkọ Ọgbin
|
Ìgbimọ Iwadi Apapọ ti US ṣiṣẹ lori ìpa ayipada óju ọjọ lori ìkórè irugbin ni ọdun 2011. Ìṣiró wọn nipè ayipada ninu ikórè lè dinkun tabi lèkin. Iwadi ọdun 2014 sọpè ikorè irugbin le dinku ni arin kèji Ọrundun pẹlu ipa to lagbara ni àgbègbè ti tropical ju àgbègbè iwọn otutu lọ.
|
20231101.yo_74575_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Weekend%20Getaway
|
Weekend Getaway
|
Weekend Getaway jẹ́ fìímù ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó jáde ní ọdún 2012. Desmond Elliot ni olùdarí fììmù àgbéléwò yìí, àwọn òṣèré tó kópa nínú rẹ̀ ni Genevieve Nnaji, Ramsey Nouah, Monalisa Chinda, Ini Edo, Uti Nwachukwu, Alex Ekubo, Bryan Okwara, Beverly Naya àti Uru Eke. Wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ mọ́kànlá, ó sí padà gba àmì-ẹ̀yẹ mẹ́rin nínú rè ní ayẹyẹ Nollywood & African Film Critics Awards (NAFCA), tí ọdún 2013. Wọ́n sì tún yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ méjì ní 2013 Best of Nollywood Awards pẹ̀lú Alex Ekubo tó padà gba àmì-èyẹ fún òṣèrékùnrin tó dára jù lọ. Fíìmù yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣeyọrí nípa ètò owó-iṣúná, nítorí àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tó kópa nínú rẹ̀.
|
20231101.yo_74576_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Uti%20Nwachukwu
|
Uti Nwachukwu
|
Uti Nwachukwu (tí wọ́n bí ní 3 August 1982) jẹ́ òṣèrékùnrin àti olóòtú ètò ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Jara. Ọ́ wá láti Ndokwa, Aboh Kingdom, agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ndokwa East, Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltà, ní Nàìjíríà.
|
20231101.yo_74576_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Uti%20Nwachukwu
|
Uti Nwachukwu
|
Uti wá láti ìdílé elénìyàn mẹ́fà. Ìpínlẹ̀ Delta ni ó dàgbà sí, ní Ughelli lójú òpópónà Uloho. Ilé-ìwé Igbenedion Education Center ló lọ láti ọdún 1993 wọ 1999. Ó gboyè ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ computer science ní University of Nigeria in Nsukka àti oyè bachelor's degree láti Benson Idahosa University ní Benin City.
|
20231101.yo_74577_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Bryan%20Okwara
|
Bryan Okwara
|
Bryan Okwara tí wọ́n tún mọ̀ sí Ikenna Bryan Okwara (tí wọ́n bí ní 9 November 1985) jẹ́ òṣẹ̀rékùnrin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó wá láti ẹ̀yà Igbo. Ó kópa nínú ìdíje kan, tó sì jẹ́ olúborí, tó sì tún gba àkọ́lẹ́ Mr. Nigeria ní ọdún 2007.
|
20231101.yo_74578_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Uru%20Eke
|
Uru Eke
|
Uru Eke (tí wọ́n bí ní October 11, 1979) jẹ́ òṣèrèbìnrin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti aṣàgbéjáde fíìmù àgbéléwò. Ó gbajúmọ̀ fún fíìmù rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Remember Me".Ó kópa gẹ́gẹ́ bí i ẹ̀dá-ìtàn Obi nínú àwọn fíìmù orí èrọ-amóhùnmáwòrán lórí Ndani TV, bí i Rumour Has It. Last Flight to Abuja, àti fíìmù ẹléẹ̀kejì tó ṣàgbéjáde, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ For Old Times' Sake. Òṣèrébìnrin náà tó fìgbà kan jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ kí ó tó darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ fíìmù ṣì máa ń wá àyè láti ṣe iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ.
|
20231101.yo_74578_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Uru%20Eke
|
Uru Eke
|
Eke wá láti ìràn Mbaise region, ní Ipinle Imo, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àmọ́ ìlú Newham, East London ní United Kingdom ni wọ́n bí i sí. Ilé-ìwé alákọ̀óbẹ̀rẹ̀ Galleywall Infants School, ní London ló lọ, kí ó tó wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, níbi tí ó ti lọ sí Gideon Comprehensive High School fún ẹ̀kọ́ girama. Láti tèíwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó padà lọ sí ìlú London, ó sì lọ sí Lewisham College, kí ó ṣẹ̀ tó lọ University of Greenwich, níbi tó ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Business Information Technology.
|
20231101.yo_74579_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ibiyemi%20Olatunji-Bello
|
Ibiyemi Olatunji-Bello
|
Wón bi Olatunji-Bello sí agbegbe Ogbowo ni Idumota, ní ípiịnlẹ̀ Èkó ninu ìwọ̀ oòrùn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ órilé èdè Naigiria ní ọjọ kẹta lelogun oṣù kẹrin, ọdun 1964. O lọ si Ile-iwe Girama Ọdọmọbìnrin Anglican ni Surulere laarin ọdun 1970 ati 1974 ati Ile-iwe giga awọn ọmọbirin mẹtodist, ni agbegbe Yaba fun Ile-iwe Atẹle giga laarin 1974 ati 1979. Fun eto-ẹkọ giga, o lọ si Lagos State College of Science and Technology, Ile iwe giga ti ilu Ibadan, nibi ti o ti gba oye oye ni fisioloji ni ọdun 1985. O gba oye oye oye nipa physiology lati University of Lagos ni 1987. O tun lọ si University of Texas ni San Antonio, Ile-iṣẹ Imọ Ilera, San Antonio laarin 1994 ati 1998.
|
20231101.yo_74579_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ibiyemi%20Olatunji-Bello
|
Ibiyemi Olatunji-Bello
|
Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ olùkọ́ ní ile iwe giga ti Ìṣègùn, fasiti ti ilu Èkó. ó sì gba ipò rẹ̀, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ó di ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìṣègùn ní Lagos State University College of Medicine ní ọdún 2007. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí igbákejì fásitì ìpínlẹ̀ Èkó (LASU) ní ọdún 2008. Bakan naa lo tun je igbakeji kanselu fasiti ipinle Eko ti a mo si LASU ko to di pe Ojogbon Ibiyemi Olatunji-Bello ti yan gege bi Igbakeji Alakoso 9th ti Eko State University (LASU). Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú The Nation, ó mẹ́nu kan pé òun di igbákejì ọ̀gá àgbà nítorí pé ó jẹ́ àkókò tí Ọlọ́run yàn fún òun.
|
20231101.yo_74579_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ibiyemi%20Olatunji-Bello
|
Ibiyemi Olatunji-Bello
|
Iyaafin Olatunji-Bello ni iyawo komisanna Bello Olutunji ti o jẹ kọmiṣanna fun ayika ati awọn orisun omi ni Ipinle Eko. Iyaafin Bello-Olutunji ni ọmọ mẹta.
|
20231101.yo_74579_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Ibiyemi%20Olatunji-Bello
|
Ibiyemi Olatunji-Bello
|
Olatunji-Bello ti Àami ẹ̀yẹ àṣeyọri Awọn obinrin ni orilẹ-ede Naijiria ni ẹka ti O tayọ julọ ni Ẹkọ Ile-ẹkọ giga.
|
20231101.yo_74580_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3amubad%E1%BB%8Dgba%20Lori%20%C3%80yip%C3%A0d%C3%A0%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Àṣamubadọgba Lori Àyipàdà Óju Ọjọ
|
Àṣamubadọgba Lori Àyipada Óju Ọjọ jẹ ọna a ti ṣè àtunṣè lori ipa ayipada óju ọjọ. Èyi jẹ ipa ti oun ṣẹlẹ lọwọ tabi eyi to nbọ. Àṣamubadọgbà jẹ ọna lati dinku tabi dina abùrù kuró fun ọmọ èniyan.
|
20231101.yo_74580_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3amubad%E1%BB%8Dgba%20Lori%20%C3%80yip%C3%A0d%C3%A0%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Àṣamubadọgba Lori Àyipàdà Óju Ọjọ
|
Èyi jẹ ọnà fun ọpọlọpọ anfani, èniyan ni lati dasi ọrọ ayipada ójù ọjọ. Óriṣiriṣi àgbèkalẹ ati ètó lo wa ni Àṣamubadọgba lati dina aburu tabi ipa awọn ìṣẹ̀lẹ̀ yii.
|
20231101.yo_74580_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3amubad%E1%BB%8Dgba%20Lori%20%C3%80yip%C3%A0d%C3%A0%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Àṣamubadọgba Lori Àyipàdà Óju Ọjọ
|
Ìdi fun Àṣamubadọgba gbẹ̀kẹlè agbègbè kan si ìkèji. Èyi lè jẹ abùrù fun èniyan tabi ayika. Àṣamubadọgba ṣè pataki fun awọn órilẹ èdè to ti dàgbà sókè nitori awọn lo maa nfarapà julọ ninu ayipada ójù ọjọ nitori idi èyi wọn maa kóju ipà ìṣẹlẹ naa. Àṣamubadọgba tobi fun ounjẹ, ómi, ọrọ àjè, iṣẹ tabi ówó ójọ.
|
20231101.yo_74580_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3amubad%E1%BB%8Dgba%20Lori%20%C3%80yip%C3%A0d%C3%A0%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Àṣamubadọgba Lori Àyipàdà Óju Ọjọ
|
Ìgbaradi ati ètó fun Àṣamubadọgba ṣè pataki órilẹ èdè lati koju abùrù to wa ni ayipàdà ójù ọjọ. Èyi ló mu ki ipèlè ijọba lati óriṣiriṣi agbègbè ṣè agbèkalẹ ètó. Awọn órilẹ ede to ti dagbàsókè maa nwa ówó lati ókè ókun ni ọna lati ṣè agbèkalẹ ètó lati ṣiṣẹ lóri Àṣamubadọgba. Ètó yii ni lati mujutó awọn ifarapa tabi èwù tolè ṣuyọ latari ayipadà ójù ọjọ. Iye owo Àṣamubadọgba ayipàdà óju ọjọ jẹ billionu dollar lọdọdun fun ọdun mẹwa to nbọ. Fun ọpọlọpọ igba, Iye owo naa dinku si bibajẹ to fẹ̀ ṣiṣẹ lori..
|
20231101.yo_74580_4
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3amubad%E1%BB%8Dgba%20Lori%20%C3%80yip%C3%A0d%C3%A0%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Àṣamubadọgba Lori Àyipàdà Óju Ọjọ
|
Ìwadi lori Àṣamubadọgba àyipàdà ójù ọjọ bẹrẹ lati ọdun 1990s. Óriṣiriṣi ọrọ lori rẹ losi ti lèkun lati igbànà. Àṣamubadọgba di ófin to mulẹ ni ọdun 2010s lati igba adehun ilẹ Paris to si sọdi ọrọ pataki fun iwàdi ófin. Ìwadi ijinlẹ sayẹnsi lori Àṣamubadọgba ayipàdà ójù ọjọ bẹrẹ pẹlù Ìtu si wẹwẹ ìpa ayipada óju ọjọ lori eniyàn, àyikà ati Ìlànà ìbáṣepọ̀ àwọn ohun ẹlẹ́mìí pẹ̀lú àyíká. Awọn Ipà nàà bóri ìṣẹmi, ètó iwósan ati àyika. Ìpayi lè jẹ ayipàdà ìkórè oun ọgbin, àlèkun ìkun ómi ati ọ̀gbẹlẹ. Ìtu si wẹwẹ awọn ipa yii jẹ ọna pataki lati mọ Àṣamubadọgba ti ọjọ iwaju.
|
20231101.yo_74580_5
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3amubad%E1%BB%8Dgba%20Lori%20%C3%80yip%C3%A0d%C3%A0%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Àṣamubadọgba Lori Àyipàdà Óju Ọjọ
|
Gẹ̀gẹbi ajọ IPCC, Ipalara ayipàdà ójù ọjọ jẹ̀ ọpọlọpọ ọna to lè jàsi èwù ati aini àgbara lati ṣè àfàràdà. Ó ṣee ṣe lati dinku èwù ni àgbègbè pẹlu fifi alawọ ewe ọgba sibẹ̀. Èyi ló dinkù óórù ati aini óunjẹ ni awọn ilu ólówó kèkèrè. Ọkan làrà ọna lati dinkù èwu ójù ọjọ ni Àṣamubadọgba Ìlànà ìbáṣepọ̀ àwọn ohun ẹlẹ́mìí pẹ̀lú àyíká. Fun àpẹrẹ, awọn ìgì to wa lèti òmi ni àgbàra lati dèna ìjì eyi lo mu ki wọn lè dèna ìkùn ómi. Ìdàbóbó igi èti ómi ni àyika jẹ ọna kan gbogi làti ṣè Àṣamubadọgba. Awọn ọna miran ni idàbóbó awùjó ati dida óhun amaàyedẹrun to lè kóju èwù silẹ.
|
20231101.yo_74580_6
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3amubad%E1%BB%8Dgba%20Lori%20%C3%80yip%C3%A0d%C3%A0%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Àṣamubadọgba Lori Àyipàdà Óju Ọjọ
|
Èsi Àṣamubadọgba pinsì àbàlà mẹrin lati dinkù èwu eyi to mù ónirùrù anfààni dani; Àṣamubadọgba ohun àmàyèdẹrun, ófin ati ilànà ijọba, àgbèkalẹ fun awùjọ ati ilè óriṣiriṣi pẹ̀lù Àṣamubadọgba Ìlànà ìbáṣepọ̀ àwọn ohun ẹlẹ́mìí pẹ̀lú àyíkà.
|
20231101.yo_74580_7
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3amubad%E1%BB%8Dgba%20Lori%20%C3%80yip%C3%A0d%C3%A0%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Àṣamubadọgba Lori Àyipàdà Óju Ọjọ
|
Órìṣiriṣi ọna lowa, eyi jẹ ṣiṣè àgbèkàlẹ ohun amàyèdẹrun lati dèna óóru, ikun ómi, alèkun ninu ipèlè ódó, ohun amayèdèruj lati kóju ayipàdà ójó ninu iṣẹ ohun ọgbin. Ohun amayèdẹrun lati fa ómi si inu ókó latari ọgbẹ̀lẹ̀.
|
20231101.yo_74580_8
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3amubad%E1%BB%8Dgba%20Lori%20%C3%80yip%C3%A0d%C3%A0%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Àṣamubadọgba Lori Àyipàdà Óju Ọjọ
|
Óunjẹ bibajẹ maa lèkun pẹlù óóru ati ìṣẹlẹ ìkun ómi. Èyi jẹ èwù fun Ounjẹ aabo ati jijẹun. Ìwọn Àgbèkalẹ̀ Àṣamubadọgba wa lati wó èrè ókó lati ọdọ awọn àgbẹ gẹgẹbi ṣiṣa èrè ókó to ba ti bàjẹ sọtọ tabi sisa awọn èrè ókó ki wọn lè gbẹ eyi lo ma dinku èwù bibajẹ. Awọn Àṣamubadọgba miran jẹ gbigba awọn èsó ti ko dàrà lọ titi, ìpin óunjẹ to ba ti pọju ati ìdinku iyè ounjẹ to ba ti fẹ bajẹ̀ fun awọn to ma tawọn ati rawọn lọja.
|
20231101.yo_74580_9
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80%E1%B9%A3amubad%E1%BB%8Dgba%20Lori%20%C3%80yip%C3%A0d%C3%A0%20%C3%93ju%20%E1%BB%8Cj%E1%BB%8D
|
Àṣamubadọgba Lori Àyipàdà Óju Ọjọ
|
Àyipada óunjẹ pẹlù jijẹ awọn óunjẹ to wa lati óun ọgbin yatọsi ti ẹran nitori awọn oun ọgbin niló agbara kèkèrè ati liló ómi ti kó pọ rara. Awọn ófin to gbèjà awọn óunjẹ yi jẹ ọna lati ṣè iwùló fun Àṣamubadọgba.Óun ọgbin pèsè óriṣiriṣi ọna fun Àṣamubadọgba, eyi jẹ̀ ayipàdà ninu igba gbingbin tabi àyipada oun ọgbin ati ẹ̀ran ọsin to ba igbà ójù ọjọ mu to si lè kóju awọm kókóró àjẹnirun. Èyi lo jẹ̀ ọna lati ṣè idabóbó óunjẹ̀.
|
20231101.yo_74581_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Tinsel%20%28TV%20series%29
|
Tinsel (TV series)
|
Tinsel jẹ́ fíìmù àgbéléwò tí wọ́n máa ń ṣàfihàn lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó bẹ̀rẹ̀ ní oṣù kẹfà, ọdún 2008. Ní ọjọ́ 23 May, ọdún 2013, wọ́n ṣàfihàn 1000th episode eré náà lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán. Ó jẹ́ fíìmù àgbéléwò orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán tó gbajúmọ jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní ọjọ́ 21 Jan, ọdún 2021, wọ́n ṣàfihàn 3000th episode eré náà.
|
20231101.yo_74581_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Tinsel%20%28TV%20series%29
|
Tinsel (TV series)
|
Àhunpọ̀ ìtàn Tinsel wáyé láàárín ilé-iṣé aṣàgbéjáde fíìmù méjì ọ̀tọ̀tọ̀ tí wọ́n di orogún ara wọn. Àkọ́kọ́ ni: Reel Studios, èyí ti Fred Ade-Williams (Victor Olaotan) ṣe ìdásílẹl rẹ̀, àti Odyssey Pictures, èyí tí Brenda "Nana" Mensah (Funmilola Aofiyebi-Raimi) jẹ́ olùdarí fún. Tinsel jẹ́ eré ajẹ́mọ́fẹ̀ẹ́, ajẹmẹ́tàn àti àlùyọ. Fíìmù náà bẹ̀rẹ̀ apá kẹjọ ní ọjọ́ 25 May, ọdún 2015.
|
20231101.yo_74581_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Tinsel%20%28TV%20series%29
|
Tinsel (TV series)
|
Fíìmù Tinsel Fíìmù wà ní ìpẹle ìṣàgbéjáde fún àádọ́rùn-ún oṣù. Àwọn òṣèré tọ́ wá fún àyẹ̀wò láti ṣe olú ẹ̀dá-ìtàn tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta, kí wọ́n ṣẹ̀ tó yan Victor Olaotan láti ṣe é. Ní oṣù June 2013, iye owó tí wọ́n fi ń ṣàgbéjáde fọ́nrán oníṣẹ̀ẹ́jú kan tó 900 dollars, tí iye àpapọ̀ náà jẹ́ four billion naira. Studio kan ní Ojota, ní Ìpínlẹ̀ Èkó ni wọ́n ti ya fọ́nrán náà, títí di oṣù March, ọdún 2013 kí iná tó ba agbègbè náà jẹ. Láti ìgbà náà ni wọ́n ti ń ya fọ́nrán náà ni agbègbè kan ní Ikeja, ní Ìpínlẹ̀ Èkó bákan náà.
|
20231101.yo_74582_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Poka
|
Poka
|
Poka jẹ idile ti ifiwera awọn ere kaadi ninu eyiti awọn oṣere nja lori iru ọwọ wo ni o dara julọ ni ibamu si awọn ofin ere kan pato. O ti wa ni dun ni agbaye, sugbon ni diẹ ninu awọn ibiti awọn ofin le yato. Nigba ti awọn earliest mọ fọọmu ti awọn ere ti a dun pẹlu o kan 20 awọn kaadi, loni o ti wa ni maa dun pẹlu kan boṣewa dekini, biotilejepe ni awọn orilẹ-ede ibi ti kukuru akopọ ni o wa wọpọ, o le wa ni dun pẹlu 32, 40 tabi 48 awọn kaadi. Bayi poka awọn ere yatọ ni dekini iṣeto ni, awọn nọmba ti awọn kaadi ni play, awọn nọmba jiya oju soke tabi koju si isalẹ, ati awọn nọmba pín nipa gbogbo awọn ẹrọ orin, ṣugbọn gbogbo awọn ni awọn ofin ti o mudani ọkan tabi diẹ ẹ sii iyipo ti kalokalo.
|
20231101.yo_74582_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Poka
|
Poka
|
Ninu ọpọlọpọ awọn ere ere poka ode oni, iyipo akọkọ ti tẹtẹ bẹrẹ pẹlu ọkan tabi diẹ ẹ sii ti awọn oṣere ti n ṣe diẹ ninu fọọmu ti tẹtẹ ti a fi agbara mu (afọju tabi ante). Ni poka boṣewa, ẹrọ orin kọọkan tẹtẹ ni ibamu si ipo ti wọn gbagbọ pe ọwọ wọn tọ bi akawe si awọn oṣere miiran. Iṣe naa lẹhinna tẹsiwaju ni iwọn aago bi oṣere kọọkan ni titan gbọdọ boya baramu (tabi “ipe”) tẹtẹ ti tẹlẹ ti o pọju, tabi agbo, padanu iye tẹtẹ bẹ jina ati gbogbo ilowosi siwaju ni ọwọ. Ẹrọ orin ti o baamu tẹtẹ le tun “gbe” (mu) tẹtẹ naa. Awọn kalokalo yika dopin nigbati gbogbo awọn ẹrọ orin ti boya ti a npe ni kẹhin tẹtẹ tabi ṣe pọ. Ti o ba jẹ pe gbogbo ẹrọ orin kan ni ipa lori eyikeyi yika, ẹrọ orin ti o ku gba ikoko naa lai nilo lati fi ọwọ wọn han. Ti o ba ti siwaju ju ọkan player si maa wa ni ariyanjiyan lẹhin ti awọn ik kalokalo yika, a showdown waye ibi ti awọn ọwọ ti wa ni han, ati awọn ẹrọ orin pẹlu awọn gba ọwọ gba ikoko.
|
20231101.yo_74582_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Poka
|
Poka
|
Ayafi ti awọn tẹtẹ fi agbara mu akọkọ, owo nikan ni a gbe sinu ikoko atinuwa nipasẹ ẹrọ orin kan ti o gbagbọ pe tẹtẹ naa ni iye ti o nireti rere tabi ti o ngbiyanju lati bluff awọn oṣere miiran fun ọpọlọpọ awọn idi ilana. Nitorinaa, lakoko ti abajade ti ọwọ eyikeyi pato ni pataki pẹlu aye, awọn ireti ṣiṣe pipẹ ti awọn oṣere ni ipinnu nipasẹ awọn iṣe wọn ti a yan lori ipilẹ iṣeeṣe, imọ-jinlẹ, ati ero ere.
|
20231101.yo_74582_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Poka
|
Poka
|
Poka ti pọ si ni gbaye-gbale lati ibẹrẹ ti ọrundun 20 ati pe o ti lọ lati jẹ iṣẹ-iṣere akọkọ ti o wa ni ihamọ si awọn ẹgbẹ kekere ti awọn alara si iṣẹ ṣiṣe ti o gbajumọ pupọ, mejeeji fun awọn olukopa ati awọn oluwo, pẹlu ori ayelujara, pẹlu ọpọlọpọ awọn oṣere alamọdaju ati ọpọlọpọ awọn dọla dọla. awọn ere idije.
|
20231101.yo_74582_4
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Poka
|
Poka
|
Lakoko ti ipilẹṣẹ gangan ti poka jẹ koko-ọrọ ariyanjiyan, ọpọlọpọ awọn ọjọgbọn ere tọka si ere Faranse Poque ati ere Persian As-Nas bi o ti ṣee ṣe ni kutukutu. Fun apẹẹrẹ, ni 1937 àtúnse ti Foster's Complete Hoyle, R. F. Foster kowe pe "ere ti poka , bi akọkọ dun ni United States, marun awọn kaadi si kọọkan player lati kan ogun-kaadi pack, jẹ laiseaniani awọn Persian ere ti As- Nàsì." Sibẹsibẹ, ni awọn ọdun 1990 ero pe poka jẹ itọsẹ taara ti As-Nas bẹrẹ si nija nipasẹ awọn onimọ-akọọlẹ ere pẹlu David Parlett. Ohun ti o daju, sibẹsibẹ, ni wipe poka ti a gbajumo ni American South ni ibẹrẹ 19. orundun, bi ayo Riverboats ni Mississippi Odò ati ni ayika New Orleans nigba ti 1830s iranwo a itankale awọn ere. Apejuwe kutukutu ti ere poka ti o dun lori ọkọ oju-omi kekere kan ni ọdun 1829 jẹ igbasilẹ nipasẹ oṣere Gẹẹsi, Joe Cowell. Awọn ere ti a dun pẹlu ogun awọn kaadi ipo lati Ace (ga) si mẹwa (kekere).
|
20231101.yo_74582_5
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Poka
|
Poka
|
Ni idakeji si ẹya ere poka yii, okunrinlada kaadi meje nikan han ni arin ọrundun 19th, ati pe o ti tan kaakiri nipasẹ ologun AMẸRIKA. O di a staple ni ọpọlọpọ awọn kasino lẹhin ti awọn keji ogun agbaye, ati ki o dagba ni gbale pẹlu awọn dide ti awọn World Series of poka ni 1970.
|
20231101.yo_74582_6
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Poka
|
Poka
|
Texas mu wọn ati awọn ere kaadi agbegbe miiran bẹrẹ lati jẹ gaba lori awọn iwoye ere ni awọn ọdun meji to nbọ. Awọn tẹlifisiọnu ti poka je kan paapa lagbara ipa jijẹ awọn gbale ti awọn ere nigba ti awọn Tan ti awọn egberun, Abajade ni poka ariwo kan ọdun diẹ nigbamii laarin 2003 ati 2006. Loni awọn ere ti po lati di ohun lalailopinpin gbajumo re pastime agbaye.
|
20231101.yo_74583_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Zubby%20Michael
|
Zubby Michael
|
Azubuike Michael Egwu tí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Zubby Michael jẹ́ òṣèré Nàìjíríà àti olùgbé eré jáde . Ó jẹ́ mímọ̀ fún ipa tí ó kó nínú Three Windows, Royal Storm àti Professional Lady. Ìfarahàn rẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ nínú eré tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Missing Rib ṣùgbọ́n ó jẹ́ mímọ̀ nínú eré The Three Windows níbi tí ó ti kó ipa tó síwájú.
|
20231101.yo_74583_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Zubby%20Michael
|
Zubby Michael
|
Zubby jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Anambra State. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Nnamdi Azikiwe University níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ mass communication.
|
20231101.yo_74583_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Zubby%20Michael
|
Zubby Michael
|
Ó bẹ̀rẹ̀ eré ìtàgé ní Yola, Ipinle Adamawa ní ìgbà èwe rẹ̀. Eré àkọ́kọ́ tí ó ti farahàn jẹ́ nínú eré tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Missing Rib ṣùgbọ́n ó gbajúmọ̀ fún ipa tó síwájú tí ó kó nínú The Three Windows. Zubby síì ti farahàn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré míràn.
|
20231101.yo_74583_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Zubby%20Michael
|
Zubby Michael
|
Ní 25 November 2019 a yan Zubby sínú ipò òṣèlú gẹ́gẹ́ bí agbani ní ìmọ̀ràn pàtàkì lórí ayélujára fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra State Gómìnà Willie Obiano. Wọ́n fún-un ní ìwé èrí ìdánimọ̀ fún akitiyan rẹ̀ lórí ètò ìróni l'àgbára fún àwọn ọ̀dọ́ ti City Radio 89.7 FM ní ìpínlè Anambra.
|
20231101.yo_74584_0
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Sama%20Raro
|
Sama Raro
|
Akpor Sama Raro (ojoibi 12 osu kejila, 1993) je omo ileewe Naijiria to ni oye akojo ninu eto oro-aje lati ile-ẹkọ giga ti Ipinle Delta. Akpor jẹ orukọ ti ara ẹni ti o jade lati ibẹrẹ ebi orukọ, Sama ni a iyipada ti awọn gangan ibi orukọ ati Raro jẹ tun kan iyipada orukọ idile akọkọ.
|
20231101.yo_74584_1
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Sama%20Raro
|
Sama Raro
|
Bi ni Oṣu kejila ọjọ 7th ni ọdun 1993 ni Ile-iwosan Warri Central. Ti gbe lati gbe ni Jos, Plateau pẹlu awọn ibatan iya titi di ọdun mejila ṣaaju ki o to lọ si Delta Nigeria. Nipasẹ ati nitorinaa ilu ilu ni Warri ti ipilẹṣẹ ni Warri nipasẹ awọn iṣẹlẹ gangan ṣaaju akoko ti o wa, botilẹjẹpe ko tii ṣe tẹlẹ ti ni itara nipa Warri nitori awọn iriri ọmọde ati awọn ipa lati gbe pẹlu awọn ibatan ti iya titi di ọdun mejila ṣaaju ki o to lọ si Warri.
|
20231101.yo_74584_2
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Sama%20Raro
|
Sama Raro
|
Sama bẹrẹ ilana ile-iwe ni awọn ile-iwe Startrite ni Ipinle Plateau ati lẹhinna tẹsiwaju nipasẹ Pinnacles International High School ni Effurun agbegbe ti Ipinle Delta ni Naijiria ṣaaju ki o to ni ifipamo gbigba wọle si Ipinle Delta University ni Akọkọ ipele ( iteriba ) akojọ lati iwadi oro aje ni odun 2019. Eko Sama ni eyi ti o jẹri pe ẹkọ jẹ iyipada anfani ti o yẹ titilai ni ihuwasi tabi agbara ihuwasi ti o waye lati iriri.
|
20231101.yo_74584_3
|
https://yo.wikipedia.org/wiki/Sama%20Raro
|
Sama Raro
|
Nifẹ ati murasilẹ fun iṣẹ, Sam jẹ oluranlọwọ nipasẹ awọn ọmọ ile-iwe giga. Nini iyasọtọ si awọn eto ẹkọ ti Ile-ẹkọ giga ti Ipinle Delta soke si professorship, ti wa ni ti o dara ju apejuwe bi ohun omowe nipa kanwa ati ojúṣe. Lẹsẹkẹsẹ lẹhin eto alefa akọkọ, Sama tẹsiwaju si awọn eto alefa giga ti Ipinle Delta Ile-ẹkọ giga ni akitiyan lati di a professor, a provost, a rector ati ki o kan Igbakeji Chancellor.
|
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.