Lọ fá irun rẹ kó tó wù. Ìbọn ló bàá l’ẹ́sẹ̀. Ọwọ́ mi ni kẹ́ẹ wò. Òṣogbo ni wọ́n ti gbé àgbò náà bọ̀. Ọ̀rúnmìlà nìkan ló gbọ́ ohùn ẹnu Olódùmarè yékéyéke. Gbénró ló pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Bí babaláwo náà ṣẹ̀ gba ibẹ̀ kọjá ni. Ọmọ bàba olówó ni mí. Abẹ́ igi Ọ̀dán ni wọ́n ti máa ń sábà pa ààlọ́. Ilẹ̀kùn yàrá Tádé ti bàjẹ́. Òǹkà Yorùbá ni mo kọ́ àwọn ènìyàn níbi ìpàdé àná. Désọ́lá lọ wẹ̀ lódò. Bàbá àgbà, ṣé ẹ ti jí? Bísí jẹ́ ìyàwó kejì. Àwọn Yorùbá kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọrọ ọmọ bíbí láwùjọ. Ẹlẹ́nu bótobòto, a ó ma wírú yó ma wírù. Mú aṣọ kúrò nílẹ̀. Wọ́n so ẹran mọ́ ‘lẹ̀ lọ́jọ́ iléyá. Ikú Olóògbé Dúró Ládiípọ̀ dun gbogbo ìlú. Arómáṣọdún bímọ ọkùnrin làǹtilanti. Òwe lẹ ó máa pa, ẹ ò ní pànìyàn. Àpò ṣaka ni wọ́n kó gbogbo ẹrù wọn sí nígbà tí wọ́n lọ sí ìrìn àjò náà. Ẹranko ti Jíbádé fẹ́ràn jù ni akọ ajá. Kí a máa dán ìgbàgbọ́ wa wò. Wọ́n mú ọmọ náà ṣeré. Àwàdà ni a fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Ẹnikẹ́ni tí ìwọ́ bá ní ipá láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún òun ni ẹnìkejì re. Láfún ni a jẹ. Mo ra ìwé mẹ́ta níbẹ̀. Ìsọkúsọ Àmọ́dù ti pọ̀ jù. Kí ló dé tò ń pè mí lánàá? Orí àdògán ni wọ́n ti ń rokà. Òòrùn ò tíì wọ̀ tán. Kí ló dé tí àwọn kan ma ń bínú tí wọ́n bá̀ ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí i è̀nìyàn sísanra? Mo ní’fẹ̀ẹ́ bí o ṣe máa ń rẹ́rìn-ín. Mo fẹ́ ra ẹyin bíbọ̀. Ilé epo náà tóbi, ẹ̀bá ọ̀nà ló wà. Owó ni kókó o. Ojúbọ òrìṣà ni owó náà wà. Àdúrà gbogbo òbí ni kí ọmọ wọ́n ṣ’oríire. Ra ọtí tàbí ẹmu fún wa. Yòrùbá bọ̀ wọ́n ní, “Kò sí bí a ó ṣe se ebòlò tí kò ní rungbẹ́.” Kò ye ká máa sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà torí a ò mọ ẹni tó lè ranni lọ́wọ́. Kò rí oorun sùn lálẹ́ àná; èyí múu bínú. Ọ̀gọ̀njọ́ òru ni àwọn eléyi tún pariwo. Ó ti jẹ gbèsè púpọ̀. Mọ fẹ́ràn ẹlẹ́dẹ̀. Ó ti sá lọ, ọ̀rọ̀ náà kọjá ohun tí agbára rẹ̀ ká. Àdùkẹ́ ti sanra ju ọjọ́ orí rẹ̀ lọ. Mi ò nífẹ̀ẹ́ sí àti máa jẹ ìgbá, mo nífẹ ọsàn dípò rẹ̀. Ṣe o ti rí ìdí tí kò fi lè tètè ní ọ̀rẹ́kùnrin. Ṣé wàá jẹ́ bàbá àwọn ọmọ mi? Orí ẹní ni mo sùn mọ́jú. Màá máa wá wò yìn nílé láìpẹ́. Ọ̀la ni ìsimi ọlọ́jọ́ gbọọrọ máa bẹ̀rẹ̀. Ọláwùnmí jẹ́ ẹni tí ó ní ìrẹ̀lẹ́. Olórí ilé aṣòfin wà ní agbègbè náà. Gbogbo èyí ni mo ti ṣe fún ẹ, ǹjẹ́ ìwọ́ lè ṣe èyí fún mi? Kòkòrò ààrùn tí ò gbóògun ti pọ̀ ní ìlú yìí. Dọ́kítà sọ pé àwọn oní gbèsè òun ò tí sanwó. Bá mi bu omi mímu wá nínu ìkòkò tó wà l'ábàáwọlé. Ṣé o wà ní oríi Twitter? Bàbá àti màmá ti lọ sí òde òkú àwọn Ṣeun. Dáre ni akọ̀wé ẹgbẹ́ akọrin inú ìjọ wa. Kò s’ẹ́ni tó mọ Ifá tán. A ti gé igi kan lulẹ̀. Ìyẹn náà ni pé àwọn ìlú kékèké nínú igbó yìí náà máa ń lo iná ìjọba. Ẹyẹlé funfun kìí bí dúdú. Ẹranko burúkú kan ló pa àwọn ẹran náà jẹ. Mo ò dára nínú eré bọ́ọ̀lù gbígbá. Lọ mú àtòrì wá l’ẹ́yìn ilẹ̀kùn. Imú ọmọ ìkókó náà dọ̀tí. Ìsàlè àpótí ni màmá máa ń kó àwọn aṣọ olówó iyebíye wọn sí. Ilé ìfowópamọ́ yapa nì agbègbè Adéọlá Ọdẹ́kù. Ìdíje ńlá gbáà ni àwọn ẹgbẹ ọdẹ ń fi Ìrèmọ̀jé Ògún ṣe. Nígbà tí ènìyàn tó burú báyì bá ń ronú kó jáwọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́, mélòómélòó ìwọ. Àkìtàn ọ̀hún wà níwájú. Alágídí l’ọmọ náà, ó fi jọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ni. Èyí já sí pé, gbogbo ìmọ̀ pátá ló ń bẹ nínú ifá. Ọ̀la ni ọdún iléyá ní Ìjẹ̀bú Òde. Yà sí apá ọ̀tún tí o bá dé Òpópónà Ìṣẹ́ri. Àgbàlá Bàbá Fọlákẹ́ ni àwọn ọmọ ti máa ń ṣ’eré ní ìrọ̀lẹ́. Ṣùgbọ́n, mo já èso kan lórí igi. Nínú gbogbo ilé ìwòsàn agbègbè yìí, ti ọ̀nà òpópónà òkìtìpupa ni ó dára díẹ̀. Mo ti lo rí ọ̀gá mi kan lorí ọ̀rọ̀ ọ̀hún. Àǹkárá olójúméje ni Ṣaléwá wọ̀. Folúkẹ́ ti múra tán kí àwọn àlejòo rẹ̀ tó dé. Ọmọ yìí ò ní àpọ́nlé kankan rárá. Ṣé o lè yá mi l’ówó títí di ìparí oṣù. Jọláadé kìí yẹ́ ṣerépá. Adéògún ti d’ọjà nù. Èròjà tí a fẹ́ fi se ọbẹ̀ kò tí ì pé o. Ó le kú, ìjà ọ̀rẹ̀. Ọkàn mí wúwo púpọ̀. Ẹ jẹ́ ká sùn díẹ̀, ṣùgbọ́n oorun ò kùn mí. Bíléèdì gé ọmọ náà ní’ka. Mí ò ṣeré o; òdodo ọ̀rọ̀ ni. Tí mo bá ti wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlájùwọ́n, ara rẹ kì í lélẹ̀. Fi ara balẹ̀ ṣá, má ṣè’jọ̀gbọ̀n. Eéwo mú mi lábẹ́ etí. Àwọn Àbẹ̀gbé yóò tó dé láti Ísírẹ́lì ní ọ̀sẹ̀ méjì sí òní. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kò káàárẹ̀ láti máa wá sí ìpàdé. Mo ò tíì wẹ láti àárọ̀. Ṣé o fẹ́ràn aṣọ tí ẹ̀gbọ́n rẹ fi ránṣẹ́ láti òkè òkun? Ìkọ̀tún ni ibi tí àwọn ayálégbé wa tẹ́lẹ̀ ń gbé báyìí. Ìkọ̀ta ni ilé tí Similólúwa ń gbé wá. Láti ojú fèrèsé mi, mo rí àwọn ọ̀dọ́ méjì tí wọ́n ń tami oge. Ilé ayé gba jẹ́jẹ́ ni bàbá máa ń sọ. Nínú gbogbo ìdáwọ́lé mi mo ríre. Koríko ni ewúrẹ́ máa ń jẹ. Ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ wa fẹ́ràn omi tútù. Ra àgbálùmọ́ fún mi tí o bá ń bọ̀. Ajò ò le dùn bí ilé. Ọjọ́ ọla mi ló jẹ mí lógún. Idà, àáké, àdá, ọfà àti ọ̀bẹ ni wọ́n fi ń jagun l’áyé àtijó. Aà jí ire bí, ẹ̀yin ọmọ Oòduà? Ìyá wa ṣe àkíyèsí ìwà ìmẹ́lẹ́ Ọmọṣẹwà, ó sì ti pèé lọ́pọ̀ ìgbà láti ba sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀. Ìyá tó mọ ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi kó má ṣe mọ ìgbẹ̀yin ayé mi. Símisọ́lá lorúkọ ìyàwó Adékúnlé. Olójú dúdú ni wá tẹ́lẹ̀. Tóbi ní òun ò fẹ́ rí ẹnikẹ́ni lénìí. Àwọn òṣìṣé ìjọba ti da’ṣé lẹ̀. Aṣọ kaánà ni t’ọko t’ìyàwó wọn wọ̀ lọ sí ilé ìjọsìn l’éni. Kí èdùmàrè dá èmí sí. Àpáta náà rí ràbàtà. Àwọn ọjà yìí ò tutù. Yéèpà, Ọbalùfọ̀n. Ọlọ́fin ní orúkọ ẹni tí ó tẹ ìlú Ọ̀tà dó. Kíni m̀bá ti ṣe sọ pé mo gbọ́? Ikọ́ burúkú wo ni ò ń wú báyìí. A fẹ́ kí wọ́n ó dàgbà kí wọn ó dògbó. Ọgbọ́n ló gbà tó bá ti jẹ́ ọ̀rọ̀ obìnrin. Àtakọ àtabo, èwo ni kì í ń ṣ’ọmọ. Ó figbe s’ẹ́nu pariwo. Ẹran ìgbẹ́ ni ìgalà àti àgbọ̀nrín. Oúnjẹ kékeré ló sè lọ fún-un. Wàhálà ti mo fi ara ṣe pò lénìí. Magí ti já ọbẹ̀ yẹn. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ òkè yìí. Àrà méèrírí, mo r’órí olóńgbò l’átẹ. Ìgbákọ tí mo fẹ́ lò dà? Ẹ̀yọ̀, Gẹ̀lẹ̀dẹ́ àti Eégún ni àwọn ọdún ìbílẹ̀ tí mo fẹ́ràn jù. Bí kò bá sí èdè kò ní sí ìtakùrọ̀sọ láàárín ọmọ ẹ̀dá ádámọ̀ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìsọkúsọ àwọn mìíràn pọ̀ jù. Oṣhòdì ni ilé iṣẹ́ Alfa wà. Ọlárótìmí fẹ́ràn ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, ohun èlò tí ó fẹ́ràn láti máa lù nìyẹn. Àpò ìwé ẹ̀ wà nínú aṣọ mi. Olúwa yóò ṣọ́ ẹ di ọjọ́ ìkúnlẹ̀ o. Ohun to yàtọ̀ pátápátá ni ọ̀la jẹ́, kò sí ẹni tó mọ̀la. Sọ fún bàba ọlọ́kọ̀ kó lọ gbé àwọn èrò tó wà ní ibùsọ̀ lọ́un yẹn. Gbogbo òbí ló ń gbàdúrà ọmọ tó máa sanjọ́. Ẹ bá mi fi díẹ̀ sí oúnjẹ yíì. Tẹ̀là ló jẹ́ kí gbogbo ọ̀rọ̀ yí lọ́di òkòtò báyìí. Ìbàjẹ́ ènìyàn ò dáṣẹ́ ọlọ́run dúró. Mo fẹ́ jẹ’kà. Àmídà ló kúrú jù ní kílàsì. Orúkọ mi ni Àdìgún Alápòméjì. Mo ní’fẹ̀ẹ́ láti bá wọn lọ fún ìnáwó náà. Ẹkùn lè ṣe ìnàkí léṣe. Ọọ̀ purọ́, bẹ́ẹ̀ gan lọ̀rọ̀ rí. Wọ́n na Àdùnní játijàti. Màmá rán mi kí n lọ ra ẹja díndín wá ní ìsọdá. Rọra máa gbá èèyàn jàre, ṣé oò mọ̀ pé ọwọ́ rẹ máa ń dùn'yan ni? Akitiyan àwọn ajíhìnrere tí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ àkọtọ́ èdè Yòrùbá kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Aṣọ funfun méje ni ó sá sí ìta. Kí ló dé tí o ní ìkáàánú fún mi tó bẹ́ẹ̀? Kí ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń da ọkàn rẹ rú? Eré orí ìtàgé náà yóò lárinrin púpọ̀. Ṣe ìlérí fún mi pé ò ní fi mí sílẹ̀. Èré orí ìtàgé ni iṣẹ́ tí Jídé Kòsókó ń ṣe. Ọmọ náà ní ìgbéraga púpọ̀. Dáfídì ní ọmọ bàba olówó ni òún jẹ́. Mo ti gba Jésù sáyé mi. Màmá mi, mo ti yó. Ẹlẹ́nu bíi ti pẹ́pẹ́yẹ ní Tamẹ́dùn. Ajíbádé fẹ́ràn obìnrin púpọ̀. Ẹ wá ra bèbí fún mi. Kìí ṣe dúndùn inú ẹnikẹ́ni kí ọmọ rẹ́ kú. Àwọn ọmọ ológbe náà náwó rẹpẹtẹ sí ayẹyẹ òkú náà. Ojúṣe àwọn olùkọ́ ni láti ríi dájú pé àwọn ọmọ tí wọn kọ́ ní òye kíkún nípa iṣẹ́ ọ̀hún. Oyún náà ti pé oṣù mẹ́jo, Ìyá Bọ́lá ò ní pẹ́ ja ẹrù náà kalẹ̀. Wọ́n máa ń lo orin dadakùádà lati fi ki oríkì ènìyàn. Inú igbó ni ẹ̀fọn máa ń wà. Wón kun àtíkè sí ọrùn Àńjọlá. Kí ni ìdí tí àwọn èyàn mìíràn fi máa ń jẹ́ àfín? Olóko ńlá ni bàbá àgbẹ̀ náà. Lára àwọn olùkọ́ tí mo ò le gbàbé ni ọ̀mọ̀wé Shèyí Kenny. Mo fi ẹnu kòó l’ẹnu. Àpadàsáburú ò ní jẹ́ ìpín wa. Ó ń gbìyànjú láti tú mi jẹ. Àgbò náà sanra. Oní wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ ni Jíbọ́lá. Yèyé mi a máa bínú ní ọ̀pọ̀ ìgbà lórí ohun tí kò tó nǹkan. Òde ò wù mí lọ. Bàbá yín ò ní pẹ́ dé o. Òpópónà náà tẹ́ rẹrẹ kárí ayé. Ta ẹ̀pà fún mi kí ebi má pa mí kú. Màálù mi ti kú. Wọ́n ti lé àwọn ẹbí Ayọ̀bámi kúrò ní agboolé. Kúnlé ti lọ ra àgádàgodo wá. Ilé ìgbọ̀nsẹ̀ náà rẹwà. Ẹní bá gẹṣin nínú mi ò ní kọ’sẹ̀. Ẹniafẹ́ sọ pé Dámilọ́lá jẹ́ kí orí òún wú. Tájù àti Tọ́lá ń lọ sí Àkúrẹ́ ní ọ̀la. Ohùn ìsàlẹ̀ ni wọ́n fi ń gbé orin náà jáde. Ìyàwó wa ti kó lọ ilé ọkọ ẹ̀. Ayé ń lọ, à ń tọ̀ ọ́. Ṣé o mọ ìdí tí mo fi sọ bẹ́ ẹ̀? Fálétí ti lọ ra àwọn ṣòkòtò ní ọjà Èjìgbò. Ojúmọ́ ire, ojúmọ́ ayọ̀. Ìṣèkúṣè ni àwọn olópàá náà ń ṣe fún wa. Ìrìn àjò ẹgbẹ̀rún ọdún, ẹsẹ̀ kan la kọ́ máa gbé. Iṣẹ́ la fẹ́ ṣe, a kìí ṣ’ọ̀lẹ. Lẹ́báa títì ni a ti rí atọ́kọ̀sẹ tí ń yẹ ọkọ̀ kan wò. Ìrẹsì àti ẹja ni èmi àti Elújọbí jẹ ní òwúrọ òní. Mo ò tí ì dé Àbújá rí. Ohun gbogbo tí Ọlórun dá, dáradára ni. Ọmọ náà kò m’ará mú, àfi bíi ará oko. Lára ibi tí a dé ni ọ̀dọ̀ Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́. Àmàlà ni Simi jẹ fún oúnjẹ ọ̀sán. Ẹlẹ́dẹ̀ náà bí ọmọ mẹ́fà péré. Òṣùwọ̀n mẹ́jọmẹ́jọ lóri omi. Ṣe o ti rí ìdí tí kò fi lè tètè ní ọ̀rẹ́bìrin? Adébọ̀wálé sọ pé òun ò mọ̀ bí aṣọ òun ṣe sọnù. Ọ̀lẹ ni ọmọ yẹn, bí mo ṣe gbọ́. Ti fèrèsé náà kí ẹfọn má baà wọlé. Gbogbo eyín Ìya Bọ̀dé ló ti yọ tán. Kátikàti bíi ọbẹ̀ onírẹsì ni gbogbo àwọn ọmọge ìsìnyín ń ṣe. Rádaràda ni gbogbo eléyìí ń ṣe. Olùṣọ́gbá ni iṣẹ́ tí mo bá ẹ rí. Dókìtà ní kí o wá sínú yàrá ìṣàyẹ̀wò. Oko obì lọ́tun, ti ọ̀gẹ̀dẹ̀ lósì. Alájápá ni iṣẹ́ tí Lọlá ń ṣe kó tó wọ iṣẹ́ Ọlọ́pàá. Wọ́n ta ọfà fun jagunjagun náà láyà. Ṣé o lè rìn kíá ju báyi lọ? Kì ń ṣe gbogbo nǹkan lèyàn ń dá sí. Onímú kékeré ni Ájàó. Ọ̀mùtí paraku ni Ọláṣayọ̀. Ẹ̀san ń bẹ fún ẹni tó bá ṣẹ̀ ìka. Ibo ni fàájì wà lálẹ́ òní? Ìmọ́tótó ṣe pàtàkì fún àti dénà ààrùn. Gẹ́rẹ́ tí wọ́n dé ọjà ni wọ́n rí wọn ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà. Mo ò ní já ẹ ku’lẹ̀. Mo fẹ́ ra ọtí fún Ìya Sùlíyá. Ijó, ẹ̀rín, ayọ̀, àti ọpẹ́ ló yẹ wá. Kọ́lá ti fi ẹsẹ̀ gún ìṣó. Mo ní àǹfààní láti dé ibi tí wọ́n ti ń hun aṣọ. Ní ìgbà kan rí kò tilẹ̀ sí lítíréṣọ̀ àpilẹ̀kọ rárá débi pé wọ́n á ní ìwé ìtàn àròsọ. Iṣan apá rẹ̀ ti já. Ìjọba ìbílẹ̀ ti ń tún àwọn ọ̀nà àdúgbò wa ṣe. Ìrèti ń bẹ, bí ẹ̀mí bá ti wà. Ògúntádé ni ó gba ìwé náà wọlé. Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ láti ilé ló mú kí ayé mi ṣì gbádùn báyìí. Ọdún Ifá jẹ́ ọdún kan pàtàkì tí a fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Elódùmarè. Wọ́n ní ká dá àjọ kí owó baà le pọ̀. A ti tọ́ka sí obì gbàǹjà àti obì àbàtà. Ata ni Bọ́láfadé ń tà láti rán ara rẹ̀ lọ sí ilé-ìwé. Ìrìn-àjò èdá láyé Ọlọ́run ló mọ̀. Ọjà ni mò ń lọ báyìí o. Ọkunrin ńlá ni Bàba Ṣọlá tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ikú á poníṣègùn bí ẹni tí o m’egbò. Mo ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà márun pẹ̀lú díẹ̀. Oṣù kẹwá ni Adéwùnmí yóò sẹ mọ̀-mí-n-mọ̀-ẹ́. Ohun tó ṣemí ní kàyéfi ni bí àwọn gẹ̀lẹ̀dẹ́ ṣe máa ń ní ìdí ńlá. Mo mọ bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ tí mo fi ń rówó. Kú iṣẹ́ takuntakun, ìwọ ọmọ yìí. Tí o bá ní jésù, ohun gbogbo lo ní. Ó darí ìpàdé náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Kí Hamid máa bú èyàn rọ̀ọ́ lọ́rùn gan. Àwọn èyàn ló sọ fún nípa ìyàwó rẹ̀ tó ń s’ágbèrè. Ọtí àmupara ni Akínbọ̀dé mu ló bá ń sọ bótobòto ní òru àná. Ṣé o ti ń ṣe ǹkan oṣù? Olórí ilé ló lágbára àti dáríji ẹni tó bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí. Mi ò gbàgbọ́ pé Tinúadé lè pa ènìyàn. Ẹni yára lòòṣà òkè ń bá dá sí tirẹ̀. Mo gbà fún ọ̀gá mi, alárẹrẹ ni wọ́n ni. Ki lo kùn sí ètè? Ohùn wa ti há. Orin dadakùádà máa ń ní ìlù lílù, ijó jíjó, ẹfẹ̀ ṣís̀e, àti oríkì. B’ólóde ò kú, òde ò lè wu gbẹ́gi. Ìròyìn agogo mẹ́sàn-án àṣálẹ́ ni bàbá ń gbó l’ọ́wọ́. Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìdí ni a lè tọ́ka sí pé ó ṣe okùnfà pípẹ́ lẹ́yìn ìwé ìtàn àròsọ Yorùbá. Ẹ̀ya Ìgbò ni ẹni tí Mọ̀rúfù fẹ́. Kò sí èyan rere kan lára ọmọ yẹn. Ẹja méjì ni wọ́n fi mu gààrí. Sé gbogbo ìgbà ni òtútù máa ń mú ìwọ ni? Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ẹ̀yà lítíréṣọ àbáláyé Yòrùbá ni eré-oníṣe àbáláyé jẹ́. Má jẹ́ kó dùn mí. Àpẹẹrẹ rere ni ó fi lé‘lẹ̀. Atá ti sá páa lórí. Ẹ yí fáànù náà sókè. Ẹ gbàdúrà kí ara wọn máa ní okun àti àláfíà. Ẹ jẹ́ kí a dá ara wa ní ara yá. Gàní ti mú kọ́kọ́rọ́ lọ. Mo kí wọn pé ‘a kú ojúmọ́’. Ó dáa kí á gbàdúrà kí a tó sùn. Ó ṣeéṣe kí ọmọ ẹ̀gbọ́n wá pá lórí bíi bàbá ẹ̀. Àwọn mélòó ló wà nínú yàrá yìíi? Ọmọ ẹlẹ́pà ti ń sá lọ. Ẹ fún mi ní àsìkò díẹ̀ síi. Ọjà Ọba jẹ́ èyí tí à ń ná ní ọrọọrún. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ó ti ṣẹ́ oyún yẹn. Àpékẹ́ ti bá mi j’íṣẹ́ fún màmá. Ọmọ ìya ológì lókè Mẹ̀sàán ni mí. Àfá ń pè’run láago márùún. Bàtà mi dà? Níbo lo kó wọn sí? Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ ò ní aṣojú mó ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Ta lo yí ẹ̀rọ amúlétutu sókè? Àrẹ̀mú ló ṣíṣẹ́ náà, ó sì ṣe dáadáa. Májìyàgbé, tìẹ ò ní gbé n’ílé ọkọ. Àyìnlá ní Kúnlé fẹ́ràn obìnrin, ṣé ọkùnrin ni kó wá fẹ́ràn ni? Èmi àti ẹ̀ jà kúrò ni ṣùgbọ́n a ti yanjú ọ̀rọ̀ náà báyìí. Ìwé mímọ́ kún fọ́nfọ́n fún ọgbọ́n àti òye. Ṣé mo jọ òmùgọ̀ ni? Àwọn ìjọba ni wọ́n gbẹ́ ibi ìpọnmi náà. Wọ́n ti gbée lọ sí Ibojì. A sọ fún-un, ṣùgbọ́n kò gbó. Mo rí pẹ́pẹ́yẹ tí ọmọ mẹ́sàn-án wà lẹ́yìn rẹ̀. Àńjọláolúwa lorúkọ àmútọ̀runwá rẹ. Àwọn Túnjí ti pààrọ̀ ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán wọn. Mo nífẹ̀ẹ́ ẹyin ojú rẹ. Olú Owólabí ló ko Ìwé ìtàn-àròsọ Ìjà Ọ̀rẹ̀. Ọjọ́ ìbí mi ń bọ̀ lọ́nà. Olú sùn fọnfọn lọ́run. Orúkọ Yorùbá jẹ́ àkàìmọye. Àdákọ ni gbogbo wọ́n ṣe. Kò kúkú sírú ọlọ́run, Ọba tí kò ṣeé pè lẹ́jọ́. Mo nílò olùkọ́ Yorùbá fún ọmọ mi. Ohùn dídùn ni wọ́n fi ń kífá. Níkẹ gbé ọmi sí Àdèyí lẹ́nu. Àwọn arẹwà obìnrin pọ̀ nílùú. Apá Káróunwí ti kán. Àwọn ẹgbẹ̀ agbábọ́ọ̀lù Nìjíríà ní àfojúsùn láti gba ife ẹ̀yẹ ti ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú tó ń lọ lọ́wọ́. Èní ni màmá Kọ́ládé yóò fi ilé ìwòsàn sílẹ̀. Fìlà náà dára lórí rẹ̀. Bá mi gbá ilẹ̀ sí Bariga. Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ìwé náà ló mọ̀wé. Mo máa ń lérò pé Bélò ní ọpọlọ ni o, àṣé orí rẹ̀ ò pé rárá. Ṣé kò f’ara pa púpọ̀? Ẹfun ni wọ́n fi ń kọ’ṣẹ́ s’ójúu pátákó. Ìrẹsì àti ẹ̀wà ni oúnjẹ tí mo fẹ́ràn jù. Wọ́n ti da ìdọ̀tí sọ́nà lẹ́ẹ̀kansíi. Oògùn abẹnu gọ̀ǹgọ̀ ni wọ́n ń pèé. Kí la fẹ́ gbà nínú ìjà. Ta ló gbé ọmọ jù sórí àkìtàn? Aṣọ ìbora wọn dà ná; níbo ni wọ́n fi sí? Èyí ni ọmọ tí mo sọ fún ẹ ní ìjẹẹ̀ta wípé ó ní ìka mẹ́fà. Kí ló dé tí àga yí fi dọ̀tí tó báyìí? Àdògán náà wà ní ẹ̀yìnkùlé. Ọládèjọ kú ikú akin. Àwọn ọsàn náà ti pọ́n. Ẹ̀yin ni atọ́kùn ètò náà, àbí? Wọ́n wà níyẹ̀wù àgbà. Ọmọ náà fẹ́ràn eré àgbéléwo bíi ẹlẹ́dàá ni. Ta ni á kó àjọ ní oṣù tó ń bọ̀. Àwọn ìjọba ti ń da ọ̀dà sí títì ìlú wa. Dàásíkí ni dókítà Ọládìjì wọ̀. Sé o sì lè bímọ sá? Fásúre jẹ́ ògbóǹtarìgì oníṣègùn ní agbègbè yìí. Ó nífẹ láti máa mú ajá rẹ̀ kiri. Ọmọ náà gbé orí mi sí àyà rẹ. Àt’àná ni mo ti ń sùn. Àwọn kan sọ pé mi ò mọ oúnjẹ sè. Ẹsítétì náà rẹwà púpọ̀. Bẹ́ẹ̀ la rí àwọn mìíràn tí ara wọ́n balẹ̀. Ìjọba ti ní kí wọ́n ti ilé náà pa nítori wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́. Ìyálẹ̀ta la wà báyìí. Ọ̀rọ̀ tí mo gbó já mi láyà púpọ̀. Ọmọ mi ti wà ní ìpele kẹrin ní ilé ìwé gíga, kí a tó rí oṣù mélo kan si, yóò ṣetán. Arẹ́gbẹ́ṣọlá ti di ògbóǹtarìgì ọ̀ta nínú ayò ọlọ́pọ́n títa ò. Ganíyá fẹ́ràn kí ó ma tọ́jà kiri. Ìwọ-oòrùn Gúsù orílẹ̀-èdè Faransé. Òwúrọ̀ kùtù hàì ni ìyá wọn máa ń gbọ́jà fún àwọn méjèèjì. Ó fẹ́ dì mọ́ọ lát’ẹ̀yìn. Ibi tí wọ́n bá fi mí sí ni mo máa ń ṣọ́. Ṣé iṣẹ́ lo fẹ́ kọ́ àbí ìwé lo fẹ́ kà? Wọ́n ti mú iná lọ kí n tó jí. Bàbá mi sọ ìtàn ìlú wa fún mi, pé láti Ìkọ̀tún la ti wá tẹ̀dó sí Ìrẹ́pọ̀ọ́dùn. Àgbélébú mi ni mo gbé rù lọ́wọ́lọ́wọ́. Ọmọ yìí ò kí ń gbọ́ràn ṣá. Ẹlẹ́hàá ni Ìyàwó Àlàhájì. Ẹ fi ṣàkì mẹ́ta sórí ìrẹsì àkọ́kọ́. Ọjọ́ àbámẹ́ta nìkan ni mo máa ma lọ sí ibiiṣẹ́. Wọ́n ńi ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ló wọlé ní ìjọba ìbílẹ̀ Kájọlà. Ọmọ bùjẹbùdànù l’Àrẹ̀mú. Mi ò ní ìdáhùn sí ìbéérè náà. Ìgbéraga kò dára rárá. Isiah àti Arógunyò ń fẹ́ obìnrin kannáà. Ṣé wàá jẹ ìrẹsì àt’ẹ̀wà? Mo ti yọ iṣẹ́ Kòfẹ́sọ̀ dànù. Nígbà kan rí, ó ní’fẹ̀ẹ́ Bọ́lá. Jẹ́ ki mọ̀ mọ tí ó bá ti ń lọ sí ilé yin. Ẹ gba Jésù s’ayé yín. Ṣé o ti rí abọ́ ẹlẹ́ta rí? Àwọn olè ja ilé ìfowópamọ́ náà. Túndé ní ìfẹ sí àti máa fi ẹ̀wà jẹ ọ̀gọ̀dẹ̀. Wọ́n pa ọmọ yín lẹ́kún. Fájídé ò ní ọpọlọ bó tilẹ̀ wù kó kéré mọ. Ọ̀dájú ọmọ pátá gbáà ni. Àwọn mìíràn ri obìrin gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tó nífẹ sí ohun ọ̀fẹ́. Ó ní ìmọ̀ púpọ́ ní ọpọlọ. Ìyàwó rẹ ní owó jùú lọ. Àwọn kọ́ọ̀sì yíì dára gan o. Ṣẹ̀ṣẹ̀ ni inú mi ń dùn. Ó wọ aṣọ kannáà tó wọ̀ lọ́sàn ijọ́ tó kọ́kọ́ kànlẹ̀kùun ẹ. Bàbá kan wà tó sọ fún egúngún pé kí ó jíṣẹ́ fún ọmọ òun pé kó fi àgùtàn rúbọ. Mo gbọ́ ìròyìn àwọn ọmọ ìyá méjì tí wọ́n fi ara wọn ṣe ògùn owó. Kí lẹ fẹ́ kọ, ṣé kí n bá ẹ kọọ́. Èdè Yorùbá dùn-ún sọ. Láti jẹ́ ọkùnrin, iṣẹ́ ńlá ni. Owó tó san ti pé. Gángan ni ọ̀rọ̀ ilé ayé, bí ó ti kọjú sẹ́nìkan, ẹ̀yìn ló kọ sẹlòmíràn. Mo fẹ́ ra àgbàdo. A fẹ́ lọ dá aṣọ náà padà sí ilé aránṣọ. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni mi ò kí bá sọ̀rọ̀ mọ́. Ojú ò ní tìyín lágbára ọlọ́run. Dáníẹ̀lì wọ bàtà dùbúlẹ̀. Ó dàbí ẹni pé àgùntàn Bísí sanra ju ti Bọ́lá lọ. Ejò náà gbé ẹran mì. Díẹ̀ ni tìẹ níbẹ̀, Abíkẹ́, ọmọ Monífádé, ara ìsokùn. Yọ ipin ojú ẹ kí o tó máa wo ti ẹlòmíràn. Oògùn ni wọ́n tà lọ́jà. Òkú kò le yin Olúwa. A rí erinmi ní Ìjẹ̀bú nínu igbó. Ẹnu-Ọwá la ti ń d’ádé. Ọ̀rẹ́ pàtàkì ni èmi àti ẹ̀gbọ́n bàbá e nígbà tó wà láyé. Ẹyin tútù ló wà. Ẹgbọ́n rẹ̀ ni ó rẹ̀ẹ́ lẹ́kún. Ọmọ iṣẹ́ méjì ló wà ní ibi iṣẹ́ yín. Ó tó gẹ́ẹ́ báyìí. Kókó àti àkàrà la fẹ́ jẹ lónìí. Àwọn ènìyàn kìí sábà fi ààrò dáná mọ́. Mo nífẹ̀ẹ́ láti máa jẹ edé. Ilé-iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ kan ní Jákànde ni ó fi ọ̀rọ̀ náà lọ̀. Yorùbá gbàgbọ́ pé àbíkú ọmọ́ wà lóríta mẹ́ta. Mary Slessor ló dáwọ́ kí a máa pa ìbejì dúró ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Mo nífẹ́ sí àwọn orin Lágbájá. Mẹ́ta ni àwọn òṣèrè Ìjẹ̀ṣa tó ń gbé ìlú yìí. Ẹní fẹ́ pẹ́ láyé, ṣé ojú rẹ̀ ò ní rí ibi? Ẹ wòó bó ṣe da ẹnú sílẹ̀. Aríṣekọ́lá ṣe dada nínú ìdánwò. Ìjá bẹ́ sílẹ̀. Àwọn ilé Èkó máa ń rí wọ́gọwọ̀gọ. Bàbá yẹn kìí gbọ́ràn, àfi’ìgbà tó bá súu. Ọ̀rọ̀ kátikàti wo lò ń sọ gan ná. Àwẹ̀ìwẹ̀tán ni omi ọ̀sà. Máa tọ́jú mi, Jèhóvà ńlá. Ọmọ náà fẹ́ràn láti ma wò mí. Àmọ̀jù ní ń b’ẹ́kùn sàáré jẹ́. Irú irun wo lo wá gé sórí báyi? Ọ̀lẹ ni ọkùnrin náà. Ta ló ni pángolo? Ìlẹ̀kẹ̀ mẹ́ta ló wà lọ́run Ọba. Ìfẹ́lódùn lorúkọ ẹgbẹ́ náà. Ọ̀dájú n'ikú, bó ṣe ń pa lọ́tùn-ún ló ń pa lósì. Ojọ́ mẹ́wa ni ó kù kí a kásẹ̀ gbogbo ètò nílẹ̀. Bàbá àti ìyá mi ló fún mi lówó tí mo ná. Mo júbà àwọn tó layé, àwọn tọ́ ti wà k’áwa tó dé. Ìwọ náà ti délẹ̀ yí, omí ti ta síi díẹ̀. Kí lò ń jẹ tó dà bí aràn yí? Adésuà mọ bí yóò ṣe bá wa mú orí rẹ̀ wá’lẹ̀. Ọmọ yẹn ní ẹwà. Kí ló dé tí irọ́ rẹ pọ̀ tó báyìí? Lára ìlú tó wà ní ẹkùn Ìlà-Oòrùn Àríwá ni Adamawa àti Bauchi. Wọ́n rí àjẹ́ kan l’ọ́san gangan n’íbàdàn. Ti ilẹ̀kùn kí o bá mi ní ojú ọ̀nà. Àkọtọ́ òde òní yàtọ̀ sí ti àtijọ́. Sítẹ́là ní ebi ń pa òun. Ògúnlàjà fẹ́ran kí àwon èèyàn ma sa òun. Akọ̀wé bàbá mi máa ń dá sí àwọn ẹjọ́ tí kò kàn-án. Àjàlá òun Àyìnlá ti ń ṣe ọ̀rẹ́ láti ìgbà kékeré wọn, inú agbolé kan ni wọ́n bí wọn sí. Orí ibùsùn yìí ni gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀. Akíntóyè ni àbígbẹ̀yìn màmá rẹ. Ipele àkọ́kọ́ ní fásitì ni mo ti pàdé ìyàwó mi. Màá ṣe iṣẹ́ náà nítorí ó dá lé orí àwọn ìwé Fágúnwà. Ẹ̀yìn ilẹ̀kùn ni a máa ń kó ìgbálẹ̀ àti ìkólẹ̀ sí. Òpó iná náà ti wó lulẹ̀. Wọ́n lọ ra ìrèké. A fẹ́ lọ ra omi ní ọjà Baṣọ̀run. Aṣọ ńlá ni ọbá máa ń wọ̀ lọ sí jímọ̀. Bọ̀dá mi yóò mú mi lọ sí ìlú òyìnbó nígbà tó bá ń padà lọ. Fi sí àarín ọkọ̀ yẹn. Yẹtí mẹ́ta ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rà fuń-un. Mo rí nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀. Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé gbogbo ohun tí Ifá sọ yìí ni wọn yó kọ sílẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ Adéṣẹwà ń jowú rẹ̀ nítorí ẹni tó ń fẹ́ nísìyí ní owó púpọ̀. Ilé olókè mẹ́rin ni wọ́n kọ́. Ṣé o ti gbọ́ nípa owó tí wọ́n ní ka fi ránsẹ́? Ohun ọmọ náà dùn. Láti ojú fèrèsé ni mo ti ń rí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Ọlọ́run má jẹ́ a rí ìjà omi. Ọjọ́ ọdún ni a bí Abíọ́dún. Atọ́batẹ́lẹ̀ ra ọ̀gẹ̀dẹ̀ wá. Bàbá mi ní ọ̀rọ̀ kán wà tí òun fẹ́ bá mi sọ. Ta ló lágbára jù nínú iwin àti egbére. Ètò ẹ̀kọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ ṣe pàtàkì. Ẹ ò ká aṣọ wọ’lé kí òjò tó bẹ̀rẹ̀. Àwọn bàbá bàba mi ló tẹ ìlé yi dó. Ilé rere ni wọ́n ti wá. Oyín ta á, ó sì sá lọ. Kò fẹ́ kí á ṣeré ìfẹ́. Kò ní mú ọgbọ́n wá tí a ò bá dá owó tó kù padà. Wákàtí kan ni mo fún ẹ láti dé ibí. Ẹ̀sìn òkèrè ni ẹ̀sin Krìstẹ́nì. Ọ̀rẹ́ mi àtàtà, kí lo fẹ́ kí n fún ẹ jẹ. Ara ò ní ni wá o. Ìdọ̀tí ti pọ̀ jù l’Ékòó. Alágídí èyàn ni Odùújókòó. Wá bá mi re èékán mi. Onímọ̀ ìṣègùn ni ọmọ mí sọ pé òun fẹ́ fẹ́. Ọpọlọ ọmọ yẹn dà bíi ti Dámilọ́lá. Ẹni rere ni alábàágbé mi ti mo sọ fún ẹ nípa ẹ̀. Mo ti fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí alága lórí ọ̀rọ̀ owó orí tí a fẹ́ san. Ǹjẹ́ o ti dé olú ìlú orílẹ̀-èdè rẹ rí? Bí bàbá bá ń rìnrìn àjò, kí wọ́n má gbé àtùpà dání. Ẹ rora sáré l’ójú ọ̀nà. Bọ̀dá Táyé ti lọ sí Mecca ní ọdún tó kọjá. Ẹsẹ̀ ń ro ó púpọ̀. Oríṣi bàtà méje ni màmá mi ńi. Aláǹgbá sáwo inú ògiri lọ. Ọlọ́run má jẹ ká r’ógun àìsàn. Mo ṣàkíyèsí wípé ọmọ náà ní ìgbéraga. Olámìdé ti gbé àtẹ wàhálà rẹ̀ dé. Wọ́n ń fá irun ara òkú náà. Ijọ́ ìgbéyàwó mi, ẹ ó ríran wò. Àwọn ọlọ́jà ò tíì dé. Akínwùnmí fẹ́ kọ́ bí wọ́n ṣe ń ka ewì. Òru ni àwọn àjẹ́ máa ń ṣe ìpàdé. Ìmọ̀ràn náà dára, a ó múu lò. Ibà ló ń ṣe é látàárọ̀. Orí páànù ni wón sá ẹran oníyọ̀ sí. Aṣọ tí ìyàwó rẹ wọ̀ gbayì, ó gbẹ̀yẹ. Àkàrà àti Ògì òyìnbó ni ìyàwó mi sè l’ówurọ̀ àná. Màmá àgbà sọ fún Lájídé pé kó lọ gba àródan wá. Ó ti jí ẹran jẹ nínú ìṣasùn. Iṣẹ́ àmúrelé tí ọ̀jọ̀gbọ́n Ajíbóyè fún wa le gidi gan o. Ọmọ ló kù ta ǹ tọ́rọ́ fún wọn. Ẹyin mẹ́fa ni kí wọ́n dín fún gbogbo yín. ọkọ̀ àlùbọ́sà ni mo rà. Mo máa lọ sí Àbújá ní oṣù kẹ̀sàán. Ẹ̀gún gún ọmọ náà lẹ́sẹ̀. Wọ́n sá eré àsápájúdé. Ẹyẹ abàmì ni ẹyẹ igún. Baba ńlá ìyà ni won ìbá jẹ tí m bá rí wọn mú. Báǹkì wo lò ń lò ná? Ta ló fi omi tí mo pọn wẹ̀. Ǹjẹ́ ó dára kí a pa iṣẹ́ jẹ bí? Oò kígbe l’óhùn rárá. Iṣẹ́ tó dára ni iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀dá èdè. Inú mí dùn lóríi bí àwọn elére ìdárayá náà ṣe fakọ́yọ lórí pápá ìṣeré. O jọ ẹni tí yóò ní ẹ̀mí gígùn. Iṣẹ́ alágbẹ̀dẹ ni bàbá mi yàn láàyò. Ọmọ náà dọ̀tí bí ẹlẹ́dẹ̀ igàn. Ilé-ifẹ̀ wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Àìsàn èjè ríru ló ṣekú pa olóyè. Gbogbo ara ni mo fi ń kí ẹ. Gbogbo àwọn ọ̀dọ́ ló fẹ́ sá kúrò l’órílẹ̀-èdè yìí. A ò ní gbà, ó ti hàn pé ẹ ti pàdé ọrẹ́ yín lọ́nà. Bí àwọn dókítà mìíràn ṣe máa ń bá’ni sọ̀rọ̀ kò daá rárá. Mo ya ìwé náà sí méjì nítorí inú bí mi gidigidi. Orí òkè náà ga gidi gan. Ilé ìjọsìn wa ni tósìn ti kọ́ dúrúu titẹ̀. Nígbà wo lò ń padà lọ sí ìlú yín ná? Àwámárììdí ni Olódùmarè. Ìdí Àràbà ni Ìyálọ́jà ń gbé. Inú balùwẹ̀ yìí ṣe ń rùn báyi? Gbogbo ara ló ń wọ́ mi. Mo fẹ́ran ilé ìtura náà. Àwọn mìíràn gbàgbó pé bí èyàn ṣe ń d’àgbà síi ló ṣe jẹ́ kó l’óye síi. Iṣẹ́ ṣí pọ̀ nílẹ̀ táa fẹ́ ṣe. Abẹ́ àtíbàbà ni ìpàdé náà yó ti wáyé. Ọlámide a máa fi gbogbo ọ̀rọ̀ ṣàwàdà, àwàdà sì máa ń kóbáa nígbà mìíràn. Ẹran ọ̀sìn ni àgùntàn, ewúrẹ́, òbúkọ, ẹlẹ́dẹ̀ àti màálù. Ọbaléndé ni mo gbà lọ sí Àjáh. Òkuta tó bàá lórí ló mú kí ẹyín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fò yọ lẹ́nu rẹ̀. Ọlọ́run, ṣàánú fún wa lórí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí. Kan ilẹ̀kùn pẹ̀lú sùúrù. Gbé kọ́ọ́pù tí ó wà ní abẹ́ ibùsùn ẹ̀gbọ́n rẹ wá. Ìyàwó ilé tí ò mọ oúnjẹ sè, kí ni ka ti gbọ́? Ṣé o ti rí ilé kòkó ní Ìbàdàn rí? Nígbà tí ogún wọ ìlú, abẹ́ àpáta ni èmi àti àwọn mòlẹ́bí mi fara ṣoko sí. Ká má baà jìyà la ṣe bí Májìyàgbé. Ibi tí mo fẹ́ yà sí pọ̀ gan. Ìbẹ́pẹ náà dùn púpọ̀. Orógbó náà gbó keke. Wọ́n ni ilé àwọn Jẹ̀lílì l’àwọn ń lò. Níjọ́ tí Herbert rí Monisọ́lá, kò lè gbójú kúrò lára rẹ̀; Ó fẹ́ẹ̀ lè ma játọ́ lẹ́nu. Túndé jẹ mí ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà. Kò sí bí igimú alágbàro ṣe gùn tó ẹni tó gbéṣẹ́ fún lọ̀gá. Kí Ajíjọlá wọlé kí á jọ ṣeré. Mo fẹ́ kúrò ní gbogbo sàkání tí wọ́n ti mọ̀ mí rí. Ìṣoore-olúwa ni orúkọ tí wọ́n fún ilé náà. Ẹ jẹ́ ká ṣeré nínú òjò. Ọgbà àjàrà ni ó yí ilé náà ká. Ẹ kú àṣekù ọdún. Ikú a sọ gbogbo ilé d’ahoro. Lọ já ewé efinrin wá. Yàrá àwọn Similólúwa tóbi gan. Ẹ̀rọ ìlọṣọ àwọn Bàba Péjú ti jó aṣọ Ìya Wálé. Àníyàn gidi ni ó fi kọ ìwé náà. Mo ti rí ìdí tí kò fi yẹ kí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi ni. Láti mú ọjọ́ ni wàhálà. Ọ̀fẹ́ ni mo gba àwọn ike náà. Ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà ni Mohammadu Buhari. Làpálàpá wà l’órí ẹ. Ìjẹta ni òjó rọ̀ kẹ́yìn. Màlú mẹ́ta la pa fún ọdún. Kádírì ń jẹun bíi wọ̀bìà. Èló ni wọ́n ń ta ìwé náà? Ẹ̀kọ́ dára púpọ̀, òun sì jẹ́ ìkan lára oun tí a nílò láti di ẹni gíga l’áwùjọ. Ọwọ́ méjì ni wọ́n kó sí inú ẹ̀. Ẹ gbé iléelẹ̀ yín wá fún àwọn agbálẹ̀. Àrá ló ya ògiri yí lulẹ̀. Omi adágún kan wà ní ẹ̀yìn ilé-ìwé mi. Àárẹ̀ náà ti wọ inú ara rẹ̀ tán. Èbìtì ò ní pa eèrà láíláí. Ayé ń sáré tètè bí ọkọ̀ akérò. Ìgbàgbọ́ mi dúró lórí olúwa. Kiní kan ti fẹ́ sí mi lójú. A ó pàdé nílé ẹjọ́ tàbí àgọ́ ọlọ́pàá. Wọ́n ti fi jọba Ìlú Alábà. Pàtàkì ni àdúrà nínú ohunkóhun. Àgbọ̀nrín mẹ́ta ń sọdá. Yànmúyańmú ń kùn sí mi létí. Moyọ̀ àti Bíbí ń bínú sí ara wọn. Wọ́n rí ọmọ tuntun kan lórí ààtàn. Àwọn ìwé náà kò dára rárá. Mò ń lọ sí ilé Ìya Ṣọlá. A ti parí ìjà wa lánàá. Ìgà ni wọ́n ń pe Àfín ní Èkó. Agége ni ilé àwọn Ọlámilékan wà. Kò sí oun tó ń bọ̀ lókè tí ilẹ̀ ò gbà. Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé gbogbo èdè kọ́ ni ó wà ní ti kíkọ sílẹ̀. Mo rí àwọn alábójútó ilé ìwòsàn kan tí ó ń mú kí ohun tí a gbà sílẹ̀ dára. Inú igbó ló wà tí àwọn agbófinró fi múu. Ayé fẹ̀ ju òṣùpá lọ nítòótọ́. Tí o bá rí ọkùnrin tí ó ń bá ẹ gbọ́ bùkátà díẹ̀, o jẹ́ má jẹ kó lọ mọ́ ẹ l’ọ́wọ́. Ìbejì ọ̀ràn ni wọ́n fẹ́ yà. Omí ti dànù. Jùwọ́n ló gbà mí sílè nígbà tí wàhálà pọ̀ fún mi. Ta ló kọ ìwé náà? Ọmọ bọ̀dá Kofí ṣubú. Ọmọ rere ni ẹ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ọṣẹ ni mo lọ rà. Ó yà mí lẹ́nu, ètè mí yà pẹ̀lú. Nínú ere àgbéléwọ̀ náà la ti rí ibi tí ọkọ ti fọ’nu fún aya rẹ̀. Rántí jẹ ohun tí ẹ gbé kalẹ̀. Mo ò gba ǹkan tì lọ́wọ́ ẹ̀. Ìfẹ́ náà múmi lọ́kàn, mi ò rí oorun sùn. Wọ́n ti mú Èmánúẹ̀lì lọ sí ibi tí yóò ti kọ́ bí wọ́n ti ń ṣe bàtà. Àwọn ọ̀rẹ́ méjì ń ya àwòrán láàárọ̀ ọjọ́ náà. Kò bìkítà bóyá ó dára tàbí kò dára. Jẹ́ ka fi bọ̀lì ṣe oúnjẹ ọ̀sán. Ọbẹ̀ náà ta sáńsán. Èdè Yorùbá ti di kíkọ sílẹ̀ kó tó di ìgbà yí pàápàá. Ilé-iṣẹ́ tí bàbá Bọ̀dé ti ń ṣiṣẹ́ ló ṣe agbátẹrù ìdíje náà. Òkédìjí ló sọ bẹ́ẹ̀ nínú ìkan lára àwọn ìwé ẹ̀. Akànlé ni bàba Àìná ń ṣe bí iṣẹ́. Kíni a mọ Ọbásanjọ́ fún? Ṣòkòtò náà dára lára rẹ̀. Ta ló mọ̀ ẹ́? Mo ò lọ sí ibìkankan pẹ̀lú ẹ. Olúwa ọba o ṣé o, mo rí isó só bẹ́ẹ̀ ni mo rí ìtọ̀ tọ̀. Mo ti gbé omi sí ẹ̀yìn ilẹ̀kùn. Ó ti dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn. Adéyanjú ni alága ìgbìmọ̀ ètò ìdìbò. Ṣe bí o ti mọ, ẹlẹ́wàa Ṣàpọ́n. Eégún kìí gba iwájú ilé wa kọjá. Iṣẹ́ ajé ló s’ọmọ nù bí òkò. Ẹ báwa s’àmín ẹ̀, oríi wa ò ní burú. Anímáṣahun ti gba ife ẹ̀yẹ tuntun. Ẹnu-Ọwá ni bàbá kọ́’lé tuntun rẹ̀ sí. Ó gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Ibi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ nìyí. À ń lọ sí Ìfẹ́lódùn lọ ṣe ayẹyẹ. Nínú èrò tí Elédùmarè fi jíǹkí ẹ̀yà Yorùbá ni ọ̀nà tí a fi ń ṣe òǹkà tó múná dóko. Wọ́n ti ń pè’run ní mọ́ṣáláṣí. Jẹ́ kí á lọ bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun níbi tí enìkan ò ti mọ̀ wá. Mo gbádùn yàrá tí mo wà. Ìṣe ẹni ní ń sọni dẹni gíga. Ṣé dáadáa lo wà lásìkò yìí. Ojú Ọlọ́bùn ni ilé ìjọsìn àwọn Tósìn wà. Bọ̀dá Ràṣídì ni wọ́n fún Òkìkí ní owó oúnjẹ àárò yìí. Ìjẹ̀bú ni bàbá ọmọ náà ti máa ń wá. Ní ìrìn-àjò tí mo lọ, mo rí odò kan tí à ń pè ní odò aláró. Ta ló fi j̣ẹ oyè Ajírọ́ba? Àmínátù ní òun fẹ́ jẹ́ kí n fẹ́ òun gẹ́gẹ́ bíi ìyàwó. Ẹniyàn mẹ́rin ló ti ra ọkọ̀ tuntun láti ọdún tó kọjá. Báwo ni mo ṣe fẹ́ parí iṣẹ́ yìí na? Olóńgbò náà ń lé eku kiri nínú ilé. Dọ́kítà ní kí wọ́n máa mu omi láàárọ̀ kùtùkùtù. Ẹ má jẹ́ kí àwọn alágbára fi ọwọ́ ńlá gbá wá lójú. Ilé-ifẹ̀ ni ọdún Ifá ti máa ń bẹ̀rẹ̀ káàkiri gbogbo àgbáńlá ayé. Àwọn ajá igbó wà nínú igbó kìjikìji náà. Orí ń fọ́ mi láti oṣù kejì. Ẹ̀gbọ́n mi ti ṣe ìgbéyàwó ní ọ̀sẹ̀ tó lọ. Aré bóòlù èní dùn. Akẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀. Mi ò mọ ẹyẹ tó ṣu Adébóyè. Fásitì Èkó ni ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Àrẹ̀mú gbà pé ó dára jù ní orílè èdè yìí. Ó bá mi mú ẹran wá. Èjì bí èjì l’àgbà ń tayò. Ikun’mú ọ̀tún ti fẹ́ bọ́ si ti òsì nígbà tí ó bí àkọ́bí rẹ̀. Àdúrà fún àwọn ológun Orílẹ̀-Èdè wa àti ìdílé wọn. Bá mi gbé ìwé wá. Ó ti ya wèrè ni? À ná tó ẹgbẹ̀rún náírà sí nǹkan ọ̀hún. Akin ti lọ ra súyà wá. Ìwé ìròyìn márùn-ún n wọ́n kọ̀ọ́ sí. A ti di àjèjì ara wa. Ejò paramọ́lẹ̀ burú púpọ̀. Ó ṣì jẹ́ ẹgbẹ ni àpo kan. Kò yé mi o, ṣé Oshòdì lo wà? Orò máa jáde lóru òní. Ẹ bu ẹmu díẹ̀ fún òun náà. Àwọn aṣọ híhun náà rẹwà púpọ̀. Nígbà tí mo ka ìwé Fágúnwà náà, mo gbé sàdáńkátà fún-un. Ṣé o ti gbọ́ nípa ọdún òkè ìtaṣe rí? Ó yẹ kí ó sọ fún mi ná kó tó di pé ó gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá àgbà. Mo rí àrà meèrírí, ó kọjá ohun tí mo ti gbọ́ tẹ́lẹ̀. Tutù ní èjí ní eyín rẹ̀. Oríṣiríṣi ìtan dówe ló wà. Ìdàgbàsókè tí ń bá ìlò ède Yorùbá nípa ìmọ̀-sáyẹ́ǹsì. Àwọn ọmọ alásẹ́wó pọ̀ lọ̀nàa Lekki. Wọ́n ti lọ fọ’bọ́ níta. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní kí ilà ó tó di oge, ó ni ohun ojú rí. Oríṣi bàtà kan ni àwọn ọmọ ìyá náà rà. Ó fún-un lọ́tí mu. Fẹ́rànmí ti wà ní ilé ìwé gíga. Ẹ̀sìn atọ̀húnrìnwá ni ẹ̀sìn ìsìlámù. Oúnjẹ ìrọ̀lẹ́ ni Ìya Kàfáyá sè. Bí ó ti ẹ̀ jẹ́ kó hàn ní ojú ẹ, mo mọ̀ pé ohun tí wọ́n ṣe dùn ẹ́ gidi. Ilé ìjọ ni a ti ṣe ọjọ́ ìbí ọ̀rẹ́ mi. Ìbọn jẹ́ irinṣẹ́ pàtàkì fún àwọn ọde. Àgbantara ni bàbá àgbà fi máa ń nara ní abẹ́ igi ọsàn. Ẹja ọbọ̀kún wà nínú ọ̀sà. Ifálékè wà ní’bẹ̀ nígbà tí ìyàwó rẹ̀ bímọ. Orin náà ń fa ọkàn mi. Àwọn tí wọ́n darí iná fún eré orí ìtàgé náà gbìyànjú. Ọ̀bọ́ bẹ́ lu ọmọ náà láti òkè. Ilẹ̀kùn méjì ni ó wà lọ́nà ọ̀run. Àgbàrá ti wọ́ oko bàbá àgbà lọ. Ọkọ̀ mẹ́ta ló takú sẹ́gbẹ̀ òpópónà. Kò sí ẹni tí kò lè dáa fún. Ẹni tó bá ń jini láya kò lè fojú ire wo’ni. Ọmọ màmá ẹ ni Túndé. Jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ fún wa. Gúsù orílẹ̀ èdè yìí ni mo ti wá. Lọ tẹ́ ibùsùn bàbá. Ó bi bàbá rẹ̀ bí òún bá lè tan ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán náà. Irun kọjúsọ́kọ ló gbé s’órí. Kọ́ọ̀sì mẹ́wa ni wọ́n ní ká ṣe. Ẹyin àtùpà náà ti fọ́. Gaàrí yẹn ti wú tó bó ṣe yẹ. Bàbá Ọba ni wọ́n ń pè wọ́n. Ọbá ti wàjà nílú Àkúrẹ́. Jẹ́ ka fò bí ẹyẹ. Tàlàbí ti ga jù. Olódùmarè ní kí ẹ má sin òrìṣà kankan lẹ́yìn òun. O sé tí o rán mi létí. Orí mi ni kẹ́ẹ wò. Ọmọ bíbí ìlú èkó ni wọ́n pè ẹ́. Kí gbogbo ayé ó wá bá wa dá sí ọ̀rọ̀ yìí, kó tó polúkúrúmuṣu. Wọ́n ti fi pamọ́ sínú ilé ìfowópamọ́. Ìyá Fátúrótì ni ó ń se ìnáwó lọ́jọ́ yẹn. Ọ̀mọ̀wé Ọládèjì wà nínú ọ́fìsì rẹ̀. Ìfé tí a fẹ́ adìyẹ ò dénú. Wọ́n ti gbé iṣẹ́ mìíràn fún mi. Onílẹ̀ gogoro ni wọ́n ń pe ọkùnrin yẹn. Mo gba ìpè oríire kan láti ìlú òyìnbó. Oùn àti iyèkan rẹ̀ ni wọ́n ń pariwo l’óru. Lára ẹbí tó gbajúmọ̀ ní ìlú Ìlọrin ni Sàràkí. Ìfọ́tí olóyì ni mo fún ọmọ tí ó wà lẹ́gbẹ ọ̀tún mi lójú àlá rẹ̀. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà rẹwà púpọ̀. Ẹ̀sìn ilẹ̀ wa ni ẹ̀sìn Àbáláyé. Gbádébọ n fà bí ìgbín. Ṣòkòtò funfun la wọ̀ lọ sí ilé ìjọsìn náà. Ẹ jẹ́ ká lọ fọṣọ wa kó baà lè mọ́. Mi ò n’ífẹ sí àpèjọ àbòsí. Àti ọjọ́ pípẹ́ làwọn baba wọ́n ti ń rejú ogun. Àwa la ó máa wá, ẹ̀yin la ó máa bá. Ó rẹ́rin músẹ́. Bàbá Adémọ́lá ti fayé sílẹ̀ láti ìgbà tí a ti wà ní ilé ìwé gíga. Mi ò fẹ́ oun tí o sọ rárá. Ilé-iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ni ìyàwó mi kejì wà. Orí omi ni wọ́n gbà sá lọ. Ìyàwó ba oko rẹ̀ nínú jẹ́. Ọbá ti gbẹ́sẹ̀ lé ìyàwó Moróunfólú. Ìjọba ìpínlẹ̀ ti tún ọ̀nà náà ṣe, ọ̀kan fún àlọ, ìkejì fún àbọ̀. Dàdàkùádà jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀na ìgbé àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Yorùbá lárugẹ. Wọ́n ti fi Akínsọ̀yínù sínú túbú. Ṣòkòto Ọlánipẹ̀kún ò balẹ̀. Lára àwọn ìwé tí mo fẹ́ràn láti máa kà ní ìgba tí mo wà ní ilé ìwé girama ni. Ìyá àgbà fi ògùsọ̀ dáná. Ọ̀tá yín ò ní sinmi lórúkọ Jésù. Orúkọ oyè Ọba Èkó náà ni àwọn mìíràn ń pè ní Elékòó. Ìfẹ́ mi si ẹ kì í ṣe tẹ̀tàn rárá. Ó ṣèṣì kọ iye owó tó ju iyé tí ó ná lọ. Aṣèyíówùú l’Ọlọ́run wa. Adébámbọ̀ mú àfẹ́sọ́nà rẹ̀ wá s’ọ́dọ̀ ìyá àgbà. Arẹwà ni ọmọbìrin náà ní gbogbo ìgbà tí mo ríi. Mo nílò èsì ìdánwò gidi fún ìtẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ mi. Ilée wa ni mo wà nígbà yẹn. A ṣèbà fún Ọba tó layé tó lọ̀run. Ní ibi ìdíje ni wọ́n ti pàdé ara wọn. Gbogbo wọn ni wọ́n ń forí balẹ̀ f'Ólúwa lati àárọ̀ di alẹ́. A máa ń rí ìjẹyọ ìlù lílù, ijó jíjó, ẹ̀fẹ̀ ṣís̀e, oríkì kíkì, èébú bíbú, ìkìlò ṣíṣe. Àwọn elétò ìlera ló ń se ìtójú fún àwọn aláàárẹ̀. Gbogbo ènìyàn ni ó ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira. Ohùn Adéyọọ́lá dà bíi ti ańgẹ́lì. Mo máa wà ní àgbègbè Tinúbú ní agogo mẹ́wa ọ̀la. Kí ló dé tí o sá aṣọ tútù sí inú ilé. Dáadáa ló yẹ ká máa ṣe. Ọlọ́run ló ni dédé lọ́dọ̀. Ṣoo lè jáde kúrò nínu yàrá mi. Inú omi ni ẹja ń gbé. Ìfọkànbalẹ̀ máa ń wà ní ọ̀pọ̀ ìgbà tí ènìyàn bá lówó lọ́wọ́. Àpáta ayérayé sebi ìsádi mi. Táyé mọ ìwé ju kẹ́hìndé lọ. Nígb̀a tí mo dé ilé wọn, bàbá wọn ni mo kọ́kọ́ rí. Èébì ń gbé ìyá olóyún yẹn. Òpẹ́bí ni àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti lọ ń ṣeré. Àwọn ará ìlú ní ìgbàgbọ́ pé ọ̀nà èrú ni ọba tuntun yí fi d’órí àléfà. Jíjí tí mo jí lówùúrọ̀ yí, ìbà rẹ ò Ọba òkè. Pọ́n ara rẹ lé kí o má baà kàbùkù. Ṣé alayé-lọ̀run ni ẹ́ ni tóo fi ń fọ́nu? Mo járọ́ọ Láídé. Kí ló lè fa kí ara máa ro èèyàn? Nígbà tí ó di ọjọ́ keje, ilẹ̀ ṣú. Bí òní ti rí ọ̀la ò lè rí bẹ́ẹ̀. Ilẹ̀ ti mọ́ bá àwọn ọ̀daràn yẹn. Kí lo fẹ́ lọ ṣe nínú ilé tí ó ti wó? Farabalẹ̀ kí o gbóhùn wọn. Mò ń jáde lọ sí ibi iṣẹ́ láti lọ gba owó oṣù. Kí Ọlọ́run jé kí orílẹ̀-èdè yí dára. Ìfẹ́ wá mi wá sílé ṣùgbọ́n mo ti lọ ìrìn àjò nígbà náà. Iyẹ̀pẹ̀ ló rọ sínú ike náà. Lọ́jọ́ tí mo dé’lu Ọba, ẹnú kọ́ láti pàdé. Lára ohun èlò aṣọ híhun ni òfì àti òwú. Bàtà tuntun náà wọ́n jojo. Àdúgbò náà máa ń dákẹ́ rọ́rọ́. Wọ́n máa gun Àràfá ní ọ̀la. Ibo ni ọkọ̀ yí ń lọ? Aláta rodo ti dé o, ṣé ẹ fẹ́ rà àbí ẹ ò rà? Àṣàkẹ́ ti lọ p’ọmi ní odò tí ó súnmọ́ Modákẹ́kẹ́. Egbére jẹ́ ìyá iwin kan. Ṣẹwẹlẹ jẹ lítíréṣọ̀ alóhun tó ń ṣe pẹ̀lú orin kíkọ, ìlù lílù, ìjó jíjó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọn ò tíì jáde ní ilé ìwé àwọn Démiláre. Ṣọ́’ra ṣe o, ayé gba jẹ́jẹ́. Wọ́n ti múná dé. Igà náà tóbi púpọ̀. Èdùmàrè jọ̀wọ́ jẹ́ káyé ó yẹ wá. Mo fẹ́ràn ìsọkúsọ lọ́jọ́ Sátidé. Ẹ̀rọ ìlọṣọ lọ̀ mí lẹ́sẹ̀. Ifálékè ti j’Ọba o. Kò sí èrò ní’ta gbangba. Ajíbádé ní òun ò lọ sí Kàdúná. Kò mọ̀ ju kí ó ma kàwé lọ. Àmì ayò mẹ́rin sí oódo ni Manchester United fi na Chelsea ní àná. Ẹni orí yọ, ó d’ilé. Àrèó máa ń fi ìwà tútù tanijẹ. Àwọn ọmọge mẹ́fà ni wọ́n ń jó ń gbìyànjú papọ̀. Omi yẹn ti tùtù ju fún mi. A tún ríi wípé o mẹ́nu bà àwọn àbíkẹ́hìn. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ olúwa fún gbogbo iṣẹ́ rere rẹ̀. Abọ́ wà nínú korobá náà. Ìrèké yi ò fi bẹ́ẹ̀ dùn bíi ti ọjà. Àsáró elépo rẹ̀dẹ̀rẹ̀dẹ̀ ni mo bá nígbà tí mo ti Ibi ṣẹ́ dé. Tí ọwọ́ rẹ́ bá kàn mí, mo ma yí omi yìí dà sí ẹ lórí. Kí Olúwa Ọba òkè jẹ́ kí ohun gbogbo rọrùn. Láti orí dé orúnkún ni òógùn ti ń bòó nígbà tí a gbóhùn ìbọn tí àwọn ọ̀daràn náà yìn. Gbogbo àwọn ìṣòwò pátápátá jẹ́ ti ìjọba. Ó fi ipá báa lò pọ̀ lánàá. Da ṣúgà náà padà sí ibi tóo ti gbée. Mo fẹ́ lọ gbafẹ́ l’ágbo fàájì. Pẹ́pẹ́yẹ máa ń wè nínú omi bẹ́ẹ̀ wọ́n ń rìn lórí ilẹ̀. Màá máa dúró dè ẹ́ ní ẹ̀bá ọ̀nà. Ògì ni màma Pamílẹ́rin ń tà. Ká máa gbàdúrà tí a bá jí dára púpọ̀. Ọ̀kan ni ènìyàn ó f’ọwọ́ mú. Ìlú wa ni wọn yó ti ṣe àṣekágbá òkú màmá àgbà kékeré. Mi ò lè wá kú nítorí iṣẹ́ ẹni ẹlẹ́ni. Wọ́n wà nílé ’gbọ̀nsẹ̀. Lọ gbo ewúro mu. Mo ti fi ìgbà kan ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ. Orin àti ìlù ṣe pàtàkì níbi eré ìdánilárayá. Abẹ́ igi ọdán ni bàbá ti ń jayé. Ní ayé àtijọ́, àwọn bàbá ni wọ́n máa ń sába ṣiṣé. Bàbá rẹ̀ ló fi ṣìná jọ. Ìgbà wo ni wọ́n ma tó se ọdún ẹ̀yọ̀. Tùràrí olóòórùn dúndùn ni wọ́n lò. Oṣù kan ààbọ̀ ni mo fi dáwó láti ra ọkọ̀ bọ̀gìnì náà. Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ èdá èdè lìgúísììkì ni mo jẹ́. Tọkọtaya ara ilẹ̀kùn náà ti bàjẹ́. Wọ́n ń dáná sí ẹ̀gbẹ́ igbó. Ọdún Olọ́jọ́ máa ń wáyé ní Ilé-Ifẹ̀. Ọdẹ náà pàdé iwin gẹ́gẹ́ bí ìtán ṣe sọ. Mú ṣíbí yẹn kúrò nílẹ̀. Lára àwọn agbẹjọ́rò àgbà ni Fálànà wà. Padà wá ní ọ̀la jàre. Kí ni m̀bá tún sọ fún ẹ ju gbogbo èyí ti mo ti sọ lọ? Fọlámí Ọlájídé lorúkọ ọ̀rẹ́ mi àtàtà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n ò fẹ́ran ọmọ náà n ò rò pé ó lè pààyàn. Ẹ̀dá nílò láti máa ní àmójúkúrò. Aṣọ àdìrẹ pọ̀ ní ìlú Abẹ́òkúta. Lábísí yasó nígbà tí à ń jẹun. Àwọn ìbejì yíì ti jọra jù. Ìyàwó àti ẹbí sì ni wọ́n jogún gbogbo rẹ̀ fún. Ǹjẹ́ o ti gbọ́ oun tó sẹlẹ̀? Tiwatọ́pẹ́ fẹ́ Tiwaladé. Jákọ́bù ń sáré yípo ọgbà náà. Mò ń lọ sí ọjà àwọn eléwé ọmọ. Ìlú ńlá ni Èkó. Wàhálà l’ọ́tùún, rògbòdìyàn l’ósì. Ṣé o fẹ́ gbé oúnjẹ síi l’ẹ́nu ni? Bàbá àgbà ti lé ní ọgọ́rin ọdún. Ẹwà rẹ pàápàá sì ṣe rẹ́gí bí ìdodo ẹ̀fọn. Ojú mi rí kí n tó ni gbogbo dúkìá yìí. Àgbà Alfa ni à ń pèé ni Rájí. Amúdá ò fẹ́ lọ kírun. Òjó ti ṣú láti ìdájí, kò dẹ̀ tíì rọ̀. Ìwádìí fi hàn pé Ògún ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó ṣe orò ìṣípá ọdẹ ní ìlú Ìrè. Ẹ má tẹ’wọ́ mọ́ọ. Ọ̀gá akọrin wa féraǹ mi gidi. Lọ fọn ikun’mú rẹ dànù. Àlákála ni Adéníkẹ lá pẹ̀lú Ayaba ẹ̀sítérì. Àyọnusọ Fàlí ti pọ̀ jù. Ìpàdé tí mo lọ lánàá, wọ́n pín owó n’íbẹ̀. Ọlárótìwọ́n sùn fọnfọn bí ẹfọ̀n. Ṣé o máa ń mutí? Bímpé ni mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ fún orílẹ̀-èdè wa. Bàba Wàídì mọ ẹni tó ni ilé epo yìí. Mo fẹ́ mu gààrí àti ẹ̀pà. Ikú M.K.O Abíọ́lá dun ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. Adé ti lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá rè láti lọ fi àwọn nǹkankan tó o létí. Kọ́kọ́rọ́ mọ́tò bàba Fáuśa ni àwọn ọmọ yìí fi ń ṣeré. Túńjí jẹ Yétúndé mí ní owó díẹ̀. Ọmọ mí ti pé oṣù mẹ́jo, ó sì ní eyín kan. Ẹdun náà ni wọ́n pè ní ọ̀bọ. Èèyàn mélo lo fẹ́ rí? Ọ̀rọ̀ tó bá ṣe àkàlàmàgbò tó fi dẹ́kún ẹ̀rín rín, bó ba ṣe gúnugún a wo koko sórí eyín. Ẹ wo omi tó sọ póun ò ní bá ẹja rẹ́, àṣé omi ọ̀hún ni yóò ṣekú pẹ́ja. Gbà jàre! Wọn wá ọmọ'bìrin kékeré kan o. Ajé f’ilé wa ṣe ibùgbé ẹ̀. Bó bá wu ẹ̀yíòwùnmí, kó má da ẹran lọ sínú igbó. Láti ibo ni oko bàbá wọn ti bẹ̀rẹ̀? Èmi ni Alága Ẹgbẹ́ Kásowọ́pọ̀. Ní ilẹ̀ Yorùbá, bàbá ni olórí ilé. Ìlú Ìlọrin ní àwon olorin dadakùádà wọ́pọ̀ sí. Ipò wo lo dì mú nínú ilé iṣẹ́ náà? Ẹlẹ́nu róbótó bí orí ìgò. Ọ̀gá ni Bísóyè Ẹlẹ́shin lọ́jọ́kọ́jọ́. Àwọn alápatà jẹ́ àwọn ènìyàn tó máa ń pa ẹran fún títà. Ṣé o ti ṣe iṣẹ́ àmúrelé rẹ? A máa ṣe tán kí oṣù tó parí. Obì jẹ́ ohun ìpanu àwọn àgbàlagbà. Ìpàdé tí mo lọ lánàá dára jọjọ. Etí ń rìn mí ṣá. Lọ mú irọ̀ yẹn wá. Orí ọ̀pẹ ni a ti máa ń rí ẹmu. Ìyàwó kékeré tí arákùnrin ọ̀hún fẹ́ ló ba gbogbo nǹkan jẹ́. Àwọn pẹ́pẹ́yẹ ń wẹ̀ nínú odò. Ṣé nítorí Ànọ́bi ni Ọlọ̀run ṣe dáa yín? Ògbójú ọdẹ ni wọ́n. Iṣẹ́ gèlè wíwé ni à ń ṣe. Lọ fi aṣọ bo omi mímu yẹn. Ọ̀jọ̀gbọ́n sàlàyé lórí rògbòdìyàn tó bẹ́ sílẹ̀ ní ìlú ọba ní àná òde oyìí. Ẹnu ọwá lọ ti ń dádé Ọba Èkó. Ẹyẹ agénifò tí ń fò Iójú ọ̀run, kílódé tóo ṣekú pa Akínsanmí? Àwo yìí tún dúró lórí omi fún ọjọ́ mẹ́tàdínlogun kí Fúnkẹ́ tó dé ibẹ̀ láti gbée lọ. Kí Ọlọ́run ṣe ohun gbogbo ní dédé. Àga irú èyí tí àwọn òyìnbó máa ń lò ni ó wà nílé Ọ̀túnba. Mo sì ń gbádun bi gbogbo nǹkan ṣe ń lọ. Ibi o bá lọ ni mo máa wá. Ta ló wà nínú ọgbà náà? A ń sọ̀rọ̀ sí Ọrẹolúwa bí ẹni tí ó níran. Ẹ yan aṣojú láàárín yìn. Àafin ọba náà ti kéré jù. Ọlọ́mọ jogún ayé; Erín jogún ọlá. Owó náà ká gbogbo ohun ta fẹ́ ṣe. Gbogbo àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú àwùjọ ní wọ́n lò láti fi ṣe àgbékalè eré àgbéléwò. Ṣé o nífẹ́ẹ̀ mi tó bí mo ṣe nífẹ́ẹ̀ rẹ bí? Ìjọba yóò fi kún owó àwọn òṣìṣẹ́. Orísìírísìí ìgbẹ́sẹ̀ ni ó máa ń jẹyọ nínú Ọdún Ifá. Tí mo bá gbàgbé ohun gbogbo, ojú rẹ ni mi ò le gbàgbé. Kí ọlọ́run fi ọ̀run kẹ́ àwọn ẹni rere. Ní àná, ọkọ mi ò wá sílé. Ọlọ́run tìẹ ni mo ṣe, ọmọ olọ́dọ̀ idẹ, àti àtíbàbá ìlẹ̀kẹ̀. Elétí kúnkun ni Túndé. Báwo la ṣe ń gbin ẹ̀gẹ́. Mi ò nífẹ sí gbogbo ìkan wọ̀nyí. Kájọlà ni ibùsọ̀ táa ma kọ́kọ́ kàn ka tó dé Káṣọpẹ́. Ọ̀pọ̀ ni ohun tí ó wà nípa ẹyẹ lèkélèké tí a ò mọ̀. Iṣu náà ti bàjẹ́. Gbogbo ohun tí mo fẹ́ ni wọ́n ṣe fún mi. Ọ̀jògbón Akínwándé wà níbi ìgbafẹ́ rẹ̀. Fúnmi dé ìgò s’ójú. Adúrú ǹkan yìí ṣẹlẹ̀, oò dẹ̀ jẹ́ kí mo gbó? Jẹ kin sìn ọ́ dé ojú ọ̀nà díẹ̀. Orí náà ń dán púpọ̀. Ajá dúdú ni ti wọn. Kí àwọn ìjọba fún àwọn ará ìlú ní amojútó àti ìbò tí ó yẹ. Mo ò nífẹ àwọn ọlọ́pàá rárá. Ó yí omi dà sínú ike mìíràn. Lọ ra ata’re wá. Òtútù ń mú ọmọ tí ń sọ ìkan fún mi yí, níṣe ló ká jọ bí i adìẹ tí òjo pa. Àyà mí máa ń já nítorí a ò mọ bí ọ̀lá ṣe máa rí. Ọpọlọ yín ni mo fẹ́ yá lò. Ifá ní pé, ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ ní kí wọ́n fi máa koná àgbo fún àwọn tí ara wọn kò yá. Ọlórun má jẹ ka wáyé òfìfo. Ọ̀rẹ́ mi tuntun tí mo ṣẹ̀ pàdé ní patí kan ni. Òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ amúnáwá náà gan mórí òpó. Wọ́n kì ń fọnu fún ọmọ ìkókó. Ohun rere ni yóò ma jẹ ti wa. Ògúndípẹ̀ ni ọ̀gá wa. Àwọn adánilárayá náà mọ̀ọ́ jó púpọ̀. Iyọ̀ pọ̀jù nínú ìrẹsì tí wón sè. Ẹ fún ọmọ l’ọ́mú fún oṣù mẹ́sàn-án. Ládúru gbogbo ìdojúkọ tí ó wà ní ọ̀nà wọn, wọ́n f’orí tìí dé òpin. Ta ló ń lọ fún ìdíje náà? Àmàlà náà gbóná fẹlifẹli. Òrìṣà, bó ò le gbèmí ṣe mí bóo ti bá mi. Èdùmàrè á fún mi l’áya rere. Kí ló dé tí wọ́n ṣẹ́ oyún fún-un? Ó ti wá hàn gbangba pé gbogbo ohun tí à ń ṣe ní àwùjọ ẹ̀dá pátápátá, eré-oníṣe ni gbogbo wọn. Yin Olúwa ìwọ ọkàn mi kì o má sì ṣe gbàgbé ore rè. Sé o lè gbà mí bí mo se rí? Géètì ilé-ìwé ni mo ti pàdé Ìsìlàmíyà ní àná. Ìlù Àyándélé ń ró kokoko. Iyá ọba náà tún wà níbẹ̀. O gbọdọ̀ gbọ́ ohun tí mo bá sọ fún ẹ, èmi ni mo bí ẹ. Ẹ wo ìdí ọ̀rọ̀ náà kí ẹ tó dájọ́. Ó fẹ́ pẹ́ láyé ju bí ó ti yẹ lọ. Orí ẹni ní ń mọ àtilà ẹni. Ìjà bẹ́ sílè láàárín Pópóọlá àti Àlùfáà mọ́ṣáláṣí wọn. Ta ló gbé aṣọ tútù sí ibí? Oò tiẹ̀ bẹ̀rù bí mo ṣe ga tó. Gèlè náà gbé ẹwà rẹ̀ jáde. Sáyídì ń ta Láfún ní agbègbè Ìta Àdó. Oorun ni Adébọ̀wálé sùn táa fi lọ táa fi dé. Olórun ìyà. Ta ló fi ọṣẹ sí ibí? Ilé tí tèmi àti àwọn akẹgbé mi dé sí rẹwà púpọ̀, ọ̀rọ̀ gan kò lè ṣàpèjúwe rẹ̀. Ẹnu ẹni la fi ń kọ mé jẹ. Ẹ̀rọ amúlétutù náà ti bàjẹ́. Ẹ máa lùú bẹ́ẹ̀, àlùbáríkà ni mo tọrọ. Ọ̀nà ibo ni mo lè gbà dé Sáfẹ́jọ́? Ẹ máa sọ̀rọ̀ yín lọ. Ṣàngó gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe fi yé wa ni aláàfin kẹta ní ìlú Ọ̀yọ́. Ẹja ọ̀bọ̀kún wù mí jẹ lónìí. Èmi ni mo bá àbúrò mi ṣe iṣẹ́ àmúrelé rẹ̀. Bá mi jìṣẹ́ fún bàbá wa. Ìlúmọ̀ọ́ká ni Olóyè Adégẹyè. Ilésanmí dùn ju oyè lọ. Pẹ̀lẹ́. O ṣé, mo ní’fẹ rẹ. Sọ ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ìwà ìbàjẹ́ nínú àwùjọ. Ẹfọ̀n mẹ́ta la gbọ́ pé ọdẹ náà pa. Àbùbùtán bíi omi òkun. Mo fẹ́ lọ sí etí òkun láti lọ gbafẹ́. Ìnuwọ́ wà ní abẹ́ tábìlì. Bíọ́dún kìí ṣọ́ owó ná rárá, ó lè ná gbogbo owó oṣù rẹ̀ tán ní ọjọ́ kan. Ohun gidi kọ́ ni k’éyàn bá ogun lọ. Àwọn dókítà fẹ́ ṣe ìyanṣẹ́lódì f’ọ́jọ́ mẹ́ta. Ìrètí nì orúkọ ọmọ àbúrò màmá mi. Jẹ́ ka lo gbafẹ́ ní Rwanda. Ọkùnrin ni adarí ìjọ náà. Wọ́n ní kí a mú àkòrí iṣẹ́ ìwádi àṣekágbá wa wá. Ohun gbogbo ló l’ẹ́san. Ọlọ́runyọmí ló tan Iwàlọlá jẹ. Ẹ̀gbọ́n mi ò sí nílé o, ẹ padà wá nírọ̀lẹ́. Àṣé ayé kọ́ la wà nílẹ̀ wa rárá, mo kí ajé kúùkàlẹ̀. Àwọn iwin inú igbó ti ń jíròrò. Ìjíròrò yó ti máa lọ lábẹ́lẹ̀ lori ètò ìdìbò tí ń bọ̀ lọ́nà. Ọdúnm̀bákú ni wọn pe ọdún náà, nítorí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀. Ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà ló fa gbogbo gbọ́nmi síi omi ò tó. Ìdí ni wípé èdè pọ̀ láwùjọ jàńtìrẹrẹ. Sa gbogbo ipá rẹ kí ọjọ́ ọ̀la rẹ́ lè suwọ̀n. Àríkẹ́adé tún ti fẹ́rakù. Ojú abẹ́rẹ́ náà ṣì ń dùn-ún. Mo fẹ́ lọ gba atẹ́gùn ní’ta. Àgbò tí a rà fún ọdún wọ́n gan ni. Ilé alájà méjì mẹ́ta, ọkọ̀ mẹ́rin, àti oko kòkó kan ni gbogbo dúkìá tí ó fi sílẹ́ lọ. Ikú kò gb’owó, kò gb’ẹ̀bẹ̀. Gbogbo aṣọ kọ́ la ń sá lóòrùn. Ọba gan ò rí ohun kankan ṣe sọ́rọ̀ ilẹ̀ yí. Àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn ti ń tako àwọn ìwé mímọ́. Àjàsín kò rántí gbé ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán fún ẹni tó ń tun-un ṣe. Mo fẹ́ lọ rí ọ̀rẹ́ mi kan ní ẹ̀yìn odi. Mo fẹ́ràn àwọn ọ̀rẹ́ mi. Àrun jẹjẹrẹ ò dára. Láti ìgbà tí Ọlákúnlé ti kàwé tán, ko tíì ríṣẹ́. Jẹ́ ka jọ lọ jẹun níta. Aya rere l’ọ́dẹ̀dẹ̀ ọkọ ni Ṣọlá. Ó ti tó lẹ̀. Lọ fi otí pa ìrònú rẹ́. Ọ́rẹ́ mi má ṣe kánjú ju kádàrá. Ṣé mò ti ṣe oun tí ó fẹ́? Bó bá yá, a ó mọ ìgbésẹ̀ tó kàn láti gbé. Àwọn ọmọ ogun orí ilẹ̀ ń bọ̀. A fẹ́ lọ wo eré ìtàgé ní Oríta Mẹ́rin. Láti mọ iṣẹ́ náà, ó gba ìfarabalẹ̀. Ilé kan wà ní Ìkòyí tí mo máa ń rí, mo fẹ́ràn ìgbékalẹ̀ rẹ̀ púpọ̀. A gbàgbọ́ pé wọ́n jẹ́ ẹ̀mí àwọn ará ọ̀run tí wọ́n máa ń bẹ ilé-ayé wò. Ẹ ò gbodọ̀ dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi. Ẹ ṣàdúà kí ikú dáwọ́ ibi rẹ̀ dúró. Yọ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ kúrò nínú iná. Ebi ń pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n o. O ṣé, mo dúpẹ́ pé ìgbàgbọ́ rẹ nínú mi ṣì múlẹ̀ ṣinṣin. Èdè mẹ́ta ni mo gbọ́ láti kékeré. Ẹsẹ̀ ẹran náà ti kán. Aago mẹ́wàá ti lù kí n tó lọ. Mo ti gun òkè Afárá rí. Bàtà ẹ ti já lẹ́yìn. Ìyá ti lọ sódò, bàbá ti lọ sóko. Tí mo bá pè ẹ́, máa dá mi lóhùn. Ìgbẹ̀yìn ní láti so rere. Nígbà tí a lọ síbẹ̀, a rí Awólọ́wọ̀ ní ìlú Ọ̀wọ̀. Ibòji máa ń palọ́lọ́, kí ló dé? Òògùn ilẹ̀ tútù ni wọ́n lò fún Ọlábíntán. Ọmọbìrin náà rẹwà púpọ̀, tẹ̀gàn ló kù. Ìrèké jẹ́ èso tó dùn bíi ṣúgà. Túwó ni wọ́n sè fún wa. Wọ́n ti dée ládé ọba. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ bọ̀gìnì bọ̀gìnì ni mo rí lóju pópó nígbà ìrìn àjò náà. Ayọ̀dèjì ló fún wọn l’ówó. Baba wa ló tún wá jọ́ba. Wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé òhún ni. Mo ní’fẹ́ aṣọ òkè. A rí kínǹiún ní ibi tí a ti lọ wo àwọn ẹranko. Iṣẹ́ èní gba omi mu. Àwọn tí wọ́n máa ń tún ilé ìgbọ̀ǹsẹ̀ ṣe ń gbíyànjù gan o. Àṣejù ni irun àyà. Mo gba ààyè ní ibi iṣé láti lè lọ fún ìrìn àjò náà. Edé mẹ́fà ni Músá fi mu Gààrí. Iṣẹ́ ni wọ́n ń wá kiri. Bọ̀dá mi mọ oúnjẹ ṣe ju tìẹ lọ. Àkàyìmọye ìwé ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Ajíbóyè Ọládìípò ti kọ. Wọ́n ti ń lo àwọn mótò ìjàpá ní ìlú yi, ọjọ́ ti pẹ́; ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín ni kò tíì dáyé́ nígbà náà. Babátúńdé ti sọ owó nù si’lé tẹ́tẹ́. Gbogbo abọ́ ló ti dọ̀tí. Kò s’ẹ́ni tí ò ní kú, tí kò ní lọ s’ọ́run. Ibo ni ìlú tí o ti wá? Tí Àpékẹ́ bá fẹ́ lọ, a máa jọ lọ. Fún mi ní ìdajì ìgò epo. Ifo ló mú Yéwandé lójú. Iná ti tán lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi. Mọ́ṣáláṣí ni mo ti lọ gba kọ́kọ́rọ́ lọ́wọ Bọ̀dé. Wọ́n ń ṣe orò ní Sàágámù lọ́wọ́lọ́wọ́. Ẹ má jẹ kí n fẹ̀fun. Òun ni ẹni àkọ́kọ́ ti mo kọ́ ní ìfẹ́ sí. Ilé ìkọ́jàsí náà kún fọnfọn. Jìnádù pa ejò gígùn. Èmi náà fẹ́ ní ọ̀rẹ́bìrin nílé. Ìlúbìnrin ni wọ́n sọ pé àwọn ń lọ. Bí ìyá náà ṣe gbé ọmọ náà pọ̀n dára jọjọ. Mo ní ìgbáfẹ́ ní agogo mẹ́san alẹ́. Orí àga ìwàásù ni àlùfáà ti fẹnu ṣáátá àwọn alábòsí inú ìjọ. Wọ́n ti múná lọ. Gbólúwaga ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ibi tí ìyá rẹ rán-an ni. Nínú bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá ni wọ́n ti jáwé olúborí. Èké Shíttù ti pọ̀ jù. Abíọ́nà ní òun lọ rí Adé ní ago mẹ́wa òní. Ọ̀gá mi ló kọ ìwé náà. Àwọn ẹlòmíì ò ní ìtẹ́lọ́rùn rárá. Àwọn ẹranko wo ló máa ń jẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀? Iná ìjọba máa ń wà dáadáa ní agbègbè Ilémobọ́lá. Tí kò bá kí ń ṣe ọ̀làjú tí ó ti gbinlẹ̀ l’Ékò ni, àwọn ìlú oko gán wà pa. Ìsọkúsọ ni Àdèlé ma ń sọ ní gbogbo ìgbà. Mo fẹ́ kí èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi jọ ma lọ sí ibẹ̀ nígbà kan náà. Abọ̀rìṣà ni yín tẹ́lẹ̀. Ìwé márùn-ún la ma rà fún kọ́ọ̀sì náà. Báyọ̀ fi ọwọ́ gé fáànù. Àwọn ọlọ́pàá ti gbá mi mú. Mo dúpẹ́ ore àtìgbàdégbà olúwa. Àwọn tí wọ́n mọ ìtàn náà ò pọ̀ rárá. Ogun jà ní ìlú náà fún ọdún méje. Àgbàdo yíyan ni mo fẹ́ jẹ sùn. Tí ẹ bá wọ inu ilé wa, àwòrán kan wà lẹ́gbe ibùsùn; Ẹ bá mi múu wá. Ọ̀dọ̀ Ṣàngó ni wọ́n ti tọrọ ọmọ náà. Ilé wa ò ní dàrú, ọ̀nà wa ò ní bàjẹ́. Irun àgbọ̀n mí ti pọ̀ jù. Àkàrà òyìnbó náà dúdú. Mo ti gbìyànjú ohun tí mo lè dá lárà. Lọ gbá ilẹ̀ àárín ilé àti ti ẹ̀yìnkùlé. Àwọn àgbò ń kan ara wọn pa. Ìyá àwọn ọmọ tí ilé wọ́n wà ní ibùdókọ̀ kẹta sí ìyín ti bá àgbèrè lọ. Ìyálé mi ti ẹ̀ bá wa lálejò lọ́sè tó kọjá. Iṣẹ́ ìran dé ìran ni iṣẹ́ ọdẹ́ jẹ́. Àtòrì ńlá ni wọ́n fi nàá. Orí ibùsùn Àdìó ni Ṣẹfíù jókòó sí. Ẹ̀dá kàn wáyé nípasẹ̀ àwọn méjì tí wọ́n sùn papọ̀, tí wọ́n sì lóyún rẹ̀. Ẹsẹ̀ àga náà ti kạ́n. Lọ se ewédú ka lè fi jẹ àmàlà ní alẹ́. Ilé ìtura tí a dé sí tóbi jọjọ, ìlú Ọ̀yọ́ ló wà. Mo ti rí àwọn àbúrò mi á ti tó ọdún márùn-ún. Òde méjì ni a ní láti dé. Lára orúkọ tó gbajúmọ̀ ni Tinúbu ń jẹ́. Àkàndùn ló mú Ìyániẃurà lọ́wọ́. Ọ̀gá ọlọ́pàá náà ló gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Wàhálà ọmọ yìí ò ní ṣ'ekú pa ẹ́ lórúkọ Jésù. Adìyẹ àti pẹ́pẹ́yẹ ni wọ́n kan pákó náà fún. Lọ gba kọ́kọ́rọ́ wá. Orí odó lo jókòó lé. Ta ló gbé ẹja àrọ̀ wá? Ìwọ̀ǹba l'omidan ń sunwọ̀n mọ. Ẹran méjì-méjì ló fi ṣe wá lálejò. Mo tiẹ̀ ríi gbọ́ pé osù tó ń bọ̀ ni ọdún ìgúnu. Mo pàdé olùdarí ilé ìwé gíga mi ní ibi ìnáwó ní ìjẹẹ̀ta. Iṣẹ́ aránṣọ ni isẹ́ tí Lọlá ń kọ́. Abẹ́rẹ́ mẹ́ta ni ó gbà sí apá rẹ̀. Ajírọ́ba l’orúkọ oyè tó jẹ lọ́dún tó kọjá, l’ásìkò ọ̀gbẹlẹ̀ tí ebi ń pa gbogbo ìlú. Ọ̀gbẹ́ni, fi mí sílẹ̀ jọ̀ọ́. Ẹni tó bá lówó lọ́wọ́ kó ṣe bí ẹni tí ò ní. Ṣé ẹ ní dòdò àti ẹran? Yé wọ́ ẹsẹ̀ nílẹ̀ mọ́. Èdè alohùn ni èdè Yorùbá. Láti ìlú Àjàṣẹ́ ni màmá ti wá. Kí ọmọ olówó má ro ọmọ tálákà pin. Ìyá àgbà ti lé ní ọgọ́ta ọdún. Olorì ní kí a pe àwọn ẹ̀sọ́ wá. Ṣé o mọ ìdí tí mo fi ṣe bẹ́ ẹ̀ bí? Ó gbèjà àbúrò rẹ̀ gan. Ààrẹ orílẹ̀ èdè ń bọ̀ ní Civic Ceter ní ọ̀la òde yìí. Mo fẹ́ran àgbàdo sísè. Bu omi ìsanwó wá fún mi, jọ̀ọ́. Ibo ni wọ́n gbé àpótí náà sí. Ìgbà tí baálé rẹ ń bínú, o f’ọwọ́ gbáa láya. Fákáyọ̀dé ni Ọba Ìbògùn. Mo máa gbìyànjú láti ríi dájú pé o jìyà ẹ̀sẹ̀ rẹ. Ní ọjà Èjìgbòmẹkùn ni a ti ra àwọn èso ọ̀hún. Àtàrí àjànàkú ni ọ̀rọ̀ náà jẹ́, kìí ṣẹrù ọmọdé. Aṣọ funfun àti fìlà olómi aró ni wọ́n pè. Amósùn ti f’ìgbà kan jẹ́ gómìnà ìṕinlẹ̀ Ògùn rí. Ìníolúwa ni orúkọ ọmọ àbúrò ìyàwó mi. Kí ló dé tí wọn ò ṣu orí fún ọmọ yìí? Àyìnlá ti lọ s’Ẹ́dẹ. Mo ra bàtà mẹ́ta l’ọ́jà Akẹ̀sán. Ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tó farahàn nínú àwọn ìlànà yìí ni àrànmọ́. Ikú p’Abírì, Àbírì ti kú. Mo ní èróngbà láti gbé àpótí ìdìbò lọ́jọ́ kan. Àìgbọ́fá là ń wò’kè, ifá kan ò sí ní párá. Gbẹ́nu sọ́un, oníbèérè ìsọlẹ́nu. Yìnyín náà pọ̀ jọjọ, ọ̀tútù ń mú. Fún mi ní ẹran àti ẹja jẹ. Láti kékeré ni mo ti ma ń gbọ́ pé obìnrin kìí fẹ́ràn kí àwọ́n pé méjì ní ọ̀ọ̀dẹ̀ ọkọ. Ọmọ mẹ́rin ni ẹran náà bí. Òyìnbó bí ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ́ ni ó máa ń sọ ní tirẹ̀. Fáànù mẹ́ta ló wà nínú yàrá ìgbàlejò. Orísìírísìí ìgbésẹ̀ la máa gbé lórí ọ̀rọ̀ yìí. Òjò náà rọ̀ ó fẹ́rẹ̀ hú òkú ọ̀lẹ. Ọ̀mọ̀wé fún ọmọ náà ní ẹ̀bun rẹpẹtẹ. Ajá máa ń jẹ ìgbẹ́ lójú ọ̀nà. Iṣẹ́ ìjọba ni ó wù mí láti ìgbà tí mo ti wà ní kékeré. Ó ti fẹ́rakú bí mo ṣe ń wòó yìí. Bàbá mi ní ọ̀la la máa lọ ra ọkọ̀ náà. Mo ní kí Òkèjọbí pè mí lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tó bá di ọ̀la. Ó dára kí ìyàwó máa ṣisẹ́. Bàrúwá ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ríi pé ohun gbogbo lọ dédé. Kòkòrò gé Baṣọ̀run jẹ. Èrí mìíràn tí ó fi ìdí ìgbàgbọ́ Yorùbá hàn nípa Àbíkú wà nínú ẹṣẹ ifá. Mo ní’fẹ̀ẹ́ àwọn ìwé D. O Fágúnwà. Hósítẹ̀lì rẹ ló ti gbé oúnjẹ fún mi. Ọlọ́kadà ló gbá ọmọ náà. Ẹ̀rọ ayélujára máa ń parọ́ nígbà mìíràn. Èmi nìkan ni mo sun yàrá mọ́jú. Adéwálé gbé egbòogi olóró wo ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ọ̀rẹ́ kìí ṣe ẹnìkan tí ó kàn ń ṣe alábàápín ìgbà tí nnkan rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀pọ̀lọ́ ló lọ́pọlọ lọ́pọ̀lọpọ̀. Jẹ́ ka jẹ búrẹ́dì àti ẹ̀wà. Ta ló wọ bàtà mi. Ilé ni ayé wà. Ẹlẹ́nu wèrèpè ni mo pèé. Dígí náà tóbi ó sì mọ́. A yẹgi fún òdaràn náà. Ta ló wà nínú ọjà náà? Ayẹyẹ náà yóò lárinrin yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Mi ò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ mí máa dàmú ẹ. Ibo lo ti lọ fọ’bọ́? Motúnráyọ̀ ló jáwé olúborí. Gbogbo aṣọ ni Tìjání kó lọ sí ìsàlẹ̀ láti lọ fọ̀. Jẹ́ kí n fún ẹ ní gbogbo ìfẹ́ mi pátápátá. Bàbángídá ti ra mọ́tò kó tó lọ sí Hajj. Àwọn ọmọ kékeké ti pọ̀ jú ní àdúgbò yẹn. Á ṣeé ṣe lágbára ọlọ́run. Orísirísi ìtàn ìwásẹ̀ ni ó sọ nípa àwọn orísun wa, láti òkè dé’lẹ̀. Tolúwa ni ilẹ̀ àti ẹ̀kún rẹ̀. Mí ò lè bá ẹ ṣé, má bí’nú. Ṣé o ti tọrọ àforíjì? Ẹni tó ti kú ò ní ìrèti mọ́. A lọ s’éjìgbò ní’jọ̀ọ́sí. Koríko pọ̀ ní agbègbè náà. Aṣọ púpọ̀ ló wà lọ́jà, lọ ra tì ẹ. Òkè àkọ́kọ́ ilé náà ni àwọn màmá ń gbé. Ṣé àwọn ọmọ yín mọ òòṣà tí wọ́n ń pè ní ìgunnu? Àwọn ọmọ aráyé ò kìí ní sùúrù. Ìyàtọ̀ gedegbe ló wà láàárín ikú àti ìyè. Kọ́lápọ̀ jábọ́ sínu gọ́tà. Nítorí àwọn ìbéèrè pàtàkì nìkan là ń gbà sílẹ̀ kí ilẹ̀ tó ṣú. Ọkọ ni bàba tó lè báa sọ̀rọ̀ ní Surulere. Kò sí Iná lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi. Àlùjó ni wọ́n ń lù lágbo Ayéfẹ́lẹ́. Pè mí l’órúkọ mi, Ṣaléwá. Oòrùn yìí mú gan-an o. Lọ bá mi ra owó sí orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi. Sé o mọ Allen Avenue? Wọ́n gbàmí tọwọ́tẹsẹ̀ ní ilé ọkọ mi. Alhaja fẹ́ràn láti máa jẹ búrẹ́dì Sẹ́nígà. Ẹniọlá ni orúkọ Màma wọn. Àmọ̀pé ni wọ́n sọ ọmọ náà, bàbá Láfẹ́nwá ló fún-un ní orúkọ yẹn. Wàhálà rẹ pòjù, Àdùnní. Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ẹ? Alóńgẹ rẹ́rin kàkàkà. Wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fun ọmọ yẹn ní inú. Pa fèrèsé dé kí o bá mi ní ìsàlẹ̀. Àwọn mẹ́sàn-an ni wọ́n jọ ń dá àjọ náà. Ara rẹ̀ kìí lélẹ̀ tó bá ti wà lẹ́gbẹ ìyàwó rẹ̀ kejì. Ó ti wá hàn gbangba gbàǹgbà pé ọ̀pọ̀ ohun tí à ń ṣe ni àwon ara ìlú fẹ́ràn. Gbogbo rẹ̀ ṣẹ̀ hàn kedere sí mi ni. Tí a bá ń sọ àṣìṣe ara wa, èyí kò ní jẹ́ kí okùn ìfẹ́ wa gùn. Ọmọ méjì ni Simi sọ pé òun fé bí. Ayélàágbé ò fẹ́ràn kí ó máa rí àwọn àlejò ní ilé rẹ̀. A ṣì ní ọ̀pọ̀ ǹkan láti mọ̀ nípa àwọn àdán àti iye ẹ̀yà tó wà. Wùnmí fẹ́ràn kí ó máa jẹ eegun. Gbọ̀gán àṣà ìbílẹ̀ ni ijó náà ti wáyé. Ó máa ń ṣe mí bíi kí a jọ máa wà ní gbogbo ìgbà. Ó wà lára àwọn ohun tí àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun ń gbà lẹ́rọ̀. Lọ gbé omi inú ọ̀rá yẹn wá. Orí ló ń sin ni táa fi ń kọ́lémọ́lé. Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ náà ti yí dànù lórí iná. Jẹ́ ka ṣeré lọ sí ìlú ọba. Wọ́n rò pé èmi ni mo sọ fún ẹ bẹ́ẹ̀. O ṣé tọ́ọ wá sí ’lé mi lónìí. A ṣe àkíyèsí pé wàhálà yí ò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ Fún mi ní sùwíìtì lá. Mo ti pinu láti má bèèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọwọ́ enìkankan. Àwọn ìyàwó ilé náà ṣàbòsí ìyálé wọn. Ó ń polówó ọjà. Alájẹṣu ọmọ ni Táíwò. Àya rẹ̀ já nígbà tó rí ẹkùn yẹn. Ìyá ọkọọ̀ rẹ ló ń pè ọ́. Ẹ̀rín máa ń pa mí nígbà tí mo bá ń gbọ́ àwọn ìpolówó kọ̀ọ̀kan. Bí eṣinṣin ṣe ń kùn lórí èso náà kò dára. Àwọn wèrè l’àwọn olóṣèlúu wa o. Iṣu àti ẹyin ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ tán. Orúkọ fífúnni kìí ṣe ohun yẹpẹrẹ, bẹ́ẹ̀ kì í ṣe bàbàrà tó bẹ́ẹ̀. Àwọn wo ló ń pariwo láàárọ̀ kùtùkùtù báyìí. Ẹyẹ́ ti gbé ọmọ adìẹ fò lọ. Mo ní àǹfààní láti dé Adó Àwáyè. Àwámárídìí ni Ifá. Ẹniafẹ́ ti parí ilé ìwé gíga. Ní ọ̀nà àkókó, wọn ò lè ní ạ̀wọn onígbá ti wá. Ṣadé ṣiṣẹ́ ìwádi lọ sí ilẹ̀ Àríwá. Èyàn mẹ́fà ló ń jẹ́ Máíkẹ̀lì ní kílàsì wa. Báyìí ni Àrẹ̀mọ ṣe fi ààfin bàbá rẹ̀ tíí se Oba ìlú sílẹ̀. Nínú ọkọ̀ táa wọ̀ lọ s’Ọ́yọ̀ ọ́, èmi Adéyọ̀ọ́lá la jọ jókòó. Mo fẹ́ kọ́ bí wọ́n ti ń tẹ dùùrù. Akíntọ́pẹ́ jẹ́ àna sí Ògúnlèsì. A gbọ́ pé wọ́n ti jí ẹní egbére lọ. Tèmítáyò ti jáde pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, wọ́n lọ sí’bi òde ìyàwó kan. Igi wà lóko. Táyà ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà bẹ́. Bóyá màá lọ ra mọ́in-mọ́in àt’ẹ̀kọ. Àwọn àgbà ló máa ń sọ pé igúnnugún kìí kú léwe. Ilẹ̀ náà kìí ṣe ilẹ̀ olómi, ẹ ó gbádùn rẹ̀. Ẹ̀yà Yorùbá ti kúrò lẹ́gbẹ́ àwọn ẹ̀yà tí wọ́n máa ń ṣe àmúlò ìlànà òǹkà àwọn èdè mìíràn. Ó lé tìróò s’ójú. Wón ní kí a wá gba ẹran ọdún. Ẹ fún-un ní omi kó mu. Àwọn ọmọ náà ti bàlágà láti lọ́kọ. Ẹni tí ò gba kádàrá yóò gba kodoro. Bákan náà ẹwẹ̀, àkíyesí tùn wà pé, àwọn okùnrin ni ó pò jù nídìí iṣẹ́ orin. Fúnmi ti sọ̀rọ̀ nípa òkè kan fún mi rí níbi ìpàdé kan ní Ìkòyí. Oríṣi obì tí a ní kò fi bẹ́ẹ̀ yé ọ̀pọ̀ ènìyàn láwùjọ wa lónìí. Àgùntàn l’ẹranko tó gọ̀ jù. Ariwo yín ti pọ̀ jù. Wọ́n na Fadérẹra ní ilé ìwé ọjọ ìsinmi. Mo fẹ́ràn aago yí. Wọ́n ti rí ọmọ Ìya Bọ̀dé gẹ́gẹ́ bí onírọ́. Awakọ̀ náà ti di òpópónà. Ikú gbígbóná ni Ikú tí Akíntọ́lá kú. Iléèwé náà tóbi púpọ̀, ogúnlọ́gọ̀ ọmọ ni wọ́n ní. Mo ò ní tó iye owó yìí. Àfín ni ọko Ìyábọ̀. Ẹ̀gbín ni ká máa bọwọ́ f’ọ́ba. Lọ gbé ẹní wá. Kí ló ń s’áré jù nínú ìjàpá àti eku. Bí ó ṣe ń dún hùrùhẹrẹ yẹn ń dẹ́rù bà mí. Àwọn orísìí oníṣègùn ló wà, tí wọ́n fẹ́ràn epo pupa láti mu. Kò sí epo nínú ẹ̀rọ ìdáná. Tó bá di ọdún tó ń bọ̀, mo fẹ́ lọ ṣe ọdún Kérésì ní ìlú mi. Mo ti gbọ́ ìmọ̀ràn ẹ. Àárin gbùngbùn àríwá ni Atikú ti wá. Afẹ́fẹ́ náà pò ju kí èyàn bọ́ aṣọ sílẹ̀ lọ. Kí ló dé tí ò ń tẹ̀ mí lọ́rùn? A dúpẹ́, Ṣé wọ́n ń bẹ lálàáfíà ara? Ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ kí á mọ̀ pé àṣà àti ìṣe Yorùbá ní ìpìlẹ̀ tí ó dára. Wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí Ifá ṣe wí. Odò kìí ṣàn kó ó má ni orísun, òwe àwọn àgbà ni. Ọmọ tí a bí tí ó ń súnkún tọ̀san tòru. A kọ́kọ́ júbà ki a tó lọ òde eré. Búgan tí bàbá mú wálé dùn púpọ̀. Ọ̀rẹ́ mi gbá bọ́ọ̀lù lẹ́ẹ̀mẹta kó tó wọlé. O sọ pé ki n má bínú. Tó bá yá ẹ ó máa bú ìjọba, ṣé ohun tí o ṣe bójú mu? Odidi oṣù mẹ́ta ni àwọn ará ilé wa yóò fi gba ìsimi lọ sí òkè òkun. Ó sì tún jẹ́ ẹ̀bùn pàtàkì láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè. Owú dúdú lowó iná. Ṣé ó ń dùn mọ́ ẹ? Afẹ́fẹ́ ń kọjálọ lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀, gbogbo ohun ń lo létòlétò. Ilé ta fi itọ́ mọ, ìrì ni yóò wóo. Òfin ìjọba ò jẹ́ kí àwọn oníṣòwò jèrè rárá. Ó rò pé màá fi orí lé ọ̀nà ìlà-oòrùn padà lọsí ilé lọ sùn fún ọjọ́ díẹ̀. Olúmóyè sọ pe ìgbà tí òun bí ọkùnrin ni inú òun dùn jù. Mo ò tíì ri irú erin tó tóbi báyìí rí. Àgbo ni Mojí ń mu kiri. Ẹ̀jẹ̀ ń yọ ní etí ẹ. Adémìlúyìí ni orúkọ tí a fẹ́ mọ ọmọ náà sí. Má fi fún mi mọ́. Àríkẹ́ ni mo yàn láàyò jùlọ nínú gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi. Ìjọ tí mo lọ lánàá wọ́n ń pariwo. àgbọn wà ní orí igi náà. Àyànmọ́ ò gbó’gun, ṣùgbọ́n ó gbọ́ àdúrà. Òkèfúnwá ti pinu láti ríi pé gbogbo ohun tí a nílò la máa rí gbà. Púpọ̀ nínú àwọn ọmọ Nàìjíríà ni wọ́n máa ń jẹ ìrẹsì. Èèwọ̀ Orìṣà, ilẹ̀ ò ní ṣú mọ́ olóore. Kí ló dé tí o lu etí méjì? Ohun tí a ó fẹnu jóná lé lórí iṣẹ́ yìí ni èdè àwùjọ àwọn agbèrò àti awakọ̀. Àwọn ẹ̀dá inú ìtàn lè jẹ́ ènìyàn tàbí ẹranko bíi ajá, Ìjàpá, àti iwin. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wọ inú kíláásì kí òjò náà to bẹ́ sílẹ̀. Ṣé o ti gbée fún ọ̀gá ẹ? Ó fẹ́rẹ̀ má sí ìlú ilẹ̀ Yorùbá kan tí wọn kìí tí ṣe ọdún ìbílẹ̀ níbẹ̀ mọ́. Kí ló lè mú kí orí máa fọ́ ni báyìí? Alòbá fi ewé wé ọṣẹ náà. Ọba Moróunfólú ò pé lóri oyè rárá, odún mẹ́ta péré ló lò. Òjó lọ ilé ní àná láti lọ mú owó ẹ̀ wá. Ọkọ ìya Bádé ti ṣaláìsí. Ìdun wà lórí ibùsùn Gbénga. Wọ́n ti ti ilé ìtajà yín pa. Ó dà bí ẹni pé ó ti rẹ olùkọ́ọ wa. Kí lẹ ṣe ń kílàsì lénìí? Mọ́ṣáláṣí wà ní ara ilé òhún. Ṣé kí a fún àwọn agbasọfọ̀? Ẹyẹ méjì ló wà lórí igi ọ̀pẹ. Ẹ ṣùpọ̀ sí ojú kan. Ọkọ́ àti àdá jẹ́ ohun èlò gbòógì fún àwọn àgbẹ̀. Kí ọba òkè jọ̀ọ́ jàre kó kà wá mọ́ àwọn onínúdídùn ọlọ́rẹ. Ewúrẹ́ ń jẹ koríko. Ó ṣẹ̀ rí’ṣẹ́ mìíràn ni. Ọ̀gá ni Sàmù nínú ká ya àwòrán aláràmbarà. Báwo ni ò bá ṣe dùn tó kí àwọn alágbára má fi agbára da èèyàn láàmú. Ọmọ jayéjayé ni àwọn ọ̀rẹ́ mi. Ìkejà ò jìnà sí Ọ̀pẹ̀bí. Wọn ò kọ́ ẹ bí wọ́n ṣe ń wa ọkọ̀ ni? Ibí lo sùn mòjú Àjòjì ni mo jẹ́ ní ilẹ̀ tí mo ti lọ ṣe ètò àgùnbánirọ̀ mi. Mo gba iwájú fásitì Ìbàdàn kọjá lónìí. Ta ló ń dìtẹ̀ mọ́ Ọba wa Aláàfin. Inú àpò ni wọ́n kó aṣọ sí. Gàní ti lọ sí Ìlúu Mẹ́kà. Ìníolúwa ti di sisí ọmọge. Kí ni àwọn ìjọba tiẹ̀ ń fi gbogbo owó tí wọ́n ń ri ṣe gan? Orúkọ ìwé náà ni Mátìíkú. Tí mo bá lè ṣe’pò kíní nínú ìdíje yi, bàbá mi á ra ẹ̀bún fún mi, èyì dá mi lójú. Wọ́n ti lọ ṣan ara wọn lẹ́yìn wàhálà púpọ̀. Kí ni ká fi ṣe yín l’álejò báyìí, ṣé ẹ ó jẹ àmàlà tàbí iyán ni ká gún? Babájídé ni adájọ́ ilé ẹjọ́ gíga tuntun tó wà ní Ìkòyí. Ìgéraga Gbénga ga tó bẹ́ẹ̀ tó jẹ́ pé kìí fẹ́ ba ẹnìkan sọ̀rọ̀. Gọ́tà náà ń rùn. Ta ló jẹ gbogbo oúnjẹ inú abọ́ tán? Inú Fáṣọpẹ́ ń bí mi. Olè náà sáré gba kọ̀rọ̀. Ọ̀làjú àti ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá ti ń mú kí àwọn àṣà àti ìṣe wá dẹnukọlẹ̀. Ọlọ́run má jẹ a ṣòfò èmí. Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa kìí yẹ̀ láéláé. Ẹran ọ̀sìn ni ewúrẹ́ àti adìyẹ. Wàyí o, kí a máa rántí pé gbogbo ohun táa bá ṣe la ma ká nikẹhìn. À ń ṣiṣẹ́ kí a tó rówó ni. A ti mú Doyin lọ sẹ́nu ìkọ́ṣẹ́. Ààfin ni wọ́n ń pe iga ní Ọ̀yọ́. Lọ ra ẹ̀pà àti gúgúrú wá. Nígbà tí ó di òru, Ìjàpá múra, ó gbé agbọ̀n kan rù. Ìyá náà pàdánù ọmọ rẹ̀ láàárín ọdún kan. Bàbá mi gbọ́ òyìnbó ṣùgbọ́n kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ọ́ sọ. Owó ẹyọ là ń ná láyé àtijọ́. Fọlá Àgòrò ni bàbá ìyàwó mi kó lọ. Mo fẹ́ràn irun orí rẹ̀. Òróró gbígbóná ta bà mí nígbà tí à ń dín ẹran. Àra mí ń ko’ná ní òru m’ọ́jú, ọpẹ́lọpẹ́ Ṣayọ̀ tó tọ́jú mi. Ọjà ńlá ni Akẹ̀sán jẹ́. Ọmọ ọ̀lẹ ò ṣeé yá ní tọ́rọ́. Ojíkutú wà ní ilé ìwé gíga ti Ìlú Èkó. Ìlù àti agogo máa ń sábà jẹyọ nínu orin. Ó pọn dandan láti rán wa létí pé Káàárọ̀ Oò Jíire ni wá. Lọ wo ẹ̀wà tí mò ń sè nínú kíṣìnì. Ìbálòpò tọkọtaya ni a ń sọ. Bàba Bísí na Bísí lálẹ́ ìjẹta. Èdè ni à ń lò ní àwùjọ èèyàn púpọ̀, kí àgbọ́yé àti àsọyé lè wà. Gbogbo ara ni mo fi kí ẹ jàre, àbúrò mi. A ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ara wa. Ní ọjọ́ ìbí Adérónkẹ́, pẹ́pẹ́yẹ p’ọmọ, a f’ilé pọtí, a f’ònà rokà. Mo ti sùn lé ọrùn mi. Ọ̀gá ni Bísóyè níbi ká máa ṣe ìwádìí nípa ìmọ̀ èrò. Ọ̀rọ̀ ìfẹ́, bí i àdánwò ni. Orí ń yún mi láti ìjẹta. Aáyán fò sí Adéọlá ní ẹ̀yìn ọrùn. Ọmọ ọkùrin yẹn dá èkááná sí. Àgbẹ̀ r’oko b’ódún dé Èdè Gẹ̀ẹ́si ti di gbajúmọ̀ láàárín àwọn èdè àgbáyé. Pọ́ọ̀lù ló bá mi wá iṣẹ́ náà. Bí Ọládùnúní àti Ọláfibọ̀ ti lè d’ẹ́sẹ̀ náà, wọn ti tọrọ àforíjì. Ire Owó ni mo yàn kó wọ’lé mi wá. Ìyá wọn ti dolóògbé. Gbogbo àwọn nǹkan tí ó ṣàjèjì sí wa nípa epo pupa ni a ti tú jáde yékéyéké. Tí mo bá rí aláboyún, àyà mí ma ń là gàràgà. Ajá là n pa b’ọ̀gún. Wọ́n pa Olúwa wa, ó sì jíǹde. Ilé ẹjọ́ ti tú ìgbéyàwó náà ká. Àwọn ọmọ ogun orí omi wà níbẹ̀. Bí ọdẹ bá ro iṣẹ́ ro ìyà inú igbó, tí ó lọ pa ẹran kò ní f’ẹ́ni kan jẹ. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní agbára jọ̀jọ̀, ó fẹ́rẹ̀ da àárín gbogbo ebí rú. Àwọn méjì ń jà lójú títì. Ẹ̀gbọ́n mi ti ṣe ìkómọ ní ọ̀sẹ̀ tó lọ. Ilé ò ní lé wa, ọ̀nà ò sì ní nà wá. Mo rò pé ẹnìkan ti tọwọ́ bọ̀ọ́ ni kò fi ṣiṣẹ́. Ìgbéyàwó kìí s’ohun kékeré. Atẹ́ ti kúrò ní ile ìwé wa. Oríṣiríṣi ọgbọ́n ni àwọn bàbá wa máa ń ta láti de ọmọ tí ó bá jẹ́ àbíkú mọ́lẹ̀. ọ̀fà ba ọmọ ogun rè l’ẹ́sẹ̀ Ẹwọ̀n egbére ni a dá fun Aníní. Akọ̀wé Ẹgbẹ́ ni Tẹ̀là. Adájọ́ dáa lébi ẹ̀sùn táa fi kàn-án. Oyíndà ti sọnù lọ́nà. Gbogbo àwọn ènìyàn náà ti lọ sí àárín ìlú. A ti parí isẹ́, a dúpẹ́. Àárò Wọnúọlá sọ mí. Irun rẹ̀ ta kókó. Àwọn ilé alájà ńlá ńlá ló wà ní ọ̀nà ibiṣẹ́ bàbá mi. A nílò ọgbà ńlá láti gbin àwọn èso náà. Ẹgbẹ̀rún ahọ́n kò tó láti yìn ọ́. A ò ní rìn ní ọjọ́ tí ebí ń pa ọ̀nà. Àwọn ènìyàn súnmọ́ olódùmárè pẹ́kípẹ́kí. À ń lùú, ó ń dun. Ọpẹ́ ló yẹ wá. Ìrìn àjò ànà ò dẹrùn rárá, ẹnu gan kò lè ròyìn rẹ̀ tán. Kẹ́ẹ tún ilé ṣe kí a tó dé. Ìgbà tí ó ti ilẹ̀ mímọ́ dé ni ó ṣe sàráà. Aṣọ ìbora náà kò nípọn. Ẹ kú ìjóko o, gbogbo ilé àti ọjà. Ta ló gbé omi tí mo pọn? Ọba nìkan ló lè jó sí ìlu gbẹ̀du. Ọba òyìnbó kìí dé Adé rẹ̀ ní gbogbo ìgbà rárá. Igi tí wọ́n fi ń koná àgbo òhún ti jó tán. Mo nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí mi púpọ̀. Àwọn olópò náà gbìyànjú púpọ̀. Àwọn ọmọ náà mọ̀ pé ó dára láti wùwà rere. Báwo ni wàá ṣe máa da ilẹ̀ sí ojú àgbàrá báyìí? Àwọn ọdẹ etílé kìí wọnú igbó kìjikìji. Tóo bá dé oko àwọn Àkànmú, wàá fẹ́ràn iṣẹ́ àgbẹ̀. Ó ti rẹ̀ wá sínú ọkọ̀ tí a wà, àti òwúrọ̀ ni ọkọ̀ náà ti ń wà wá kiri. Búrẹ́dì ni wón tà ní iwájú ṣọ́ọ̀ṣì yìí tẹ́lẹ̀. Òrìsà ọmọ ni Òrìsà Ọ̀sun. Ó máa ń ni elégbè rẹ̀ lọ́dọ̀. Ilé ẹ̀kọ́ girama tó wà ní Jíbówú ni Akíntádé ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni gbogbo wa, àbí? Ìdí rèé tí ó fi jẹ́ pé àwọn àgbà ilé, bíi báálẹ̀, ló máa ń fún ọmọ tuntun lórúkọ. Ìyàwó Adéfarasín bàá nínú jẹ́. Lára àwọn ohun tí a fi máa ń dáná nílé ni ìkòkò àti àdògán. Ibi ọ̀rẹ́ náà ló ti ń bẹ̀rẹ̀. Ilé ilẹ̀ náà ti kún. Ọmọ Ọba ni Adédọlápọ̀. Àlùfáà yín tuntun ti ṣiṣẹ́ ní ìjọ wa rí. Ó yẹ kí a gbádùn ayé ni. Nígbà tí a wà ní kékeré ìya Lábísí máa ń na ẹni tó bá súfe nínú ilé. Nínú yàrá náà, ènìyàn márùn-ún ló ń sùn síbẹ̀. Ọ̀rẹ́ làwọn máràrùn. Ó bí ìkẹta, bákan náà tún ni. Àwọn adájọ́ mẹ́sàn-an ni wọ́n dá ẹjọ́ náà. Ibo ni Sànúsí wà? Wẹ̀mímọ́ rò pé òún gbọ́n. Ọ̀kẹ́rẹ́ náà sá gorí igi. Ǹjẹ́ ìwọ́ tí dé Ìdúmọ̀tà rí? Títa ni àkekèé máa ń tani. Ọ̀gágun Abéégúnrín àti àwọn ọmọ ogun àpapọ̀ ti lọ sí ojú ogun. Mo y’ọjú wo àwọn àlejò náà l’átòkè. Mí o gbé omí dání. Oyè jíjẹ jẹ́ oun tí a máa ń lò láti bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn jànkanjànkàn. Ìrìn àjò yí lárinrin láìní àwọn kọ́núukọ́họ kankan kankan.. Inú omi àti orílẹ̀ ni èyàn ti lè rí ọ̀ọ̀nì. Àbẹ̀kẹ́ mu àgbo títí tí ó fi fẹ́ bì. Ikú dóró, ó mú ìyá àgbà kékeré lọ! Nígbà tí ọmọ yìí dàgbà, ó tọ́jú ilé àti ọgbà. Wàyí, ó ye ká yànàná rẹ̀ wípé bí a ṣe ń lo èdè yàtọ̀ sí ara wọn. Ṣé o ti gbé ẹ̀bùn ọ̀hún fún ẹni tí mo rán ẹ sí? A ti sanwó tí wọ́n ní ká san. Ǹjẹ́ ó ṣeéṣe kí Àrólé pa ọ̀rẹ́ rè? Wọ́n gbin òdòdó sí àárín ọgbà ilé náà. A ti tọ́ka sí igi obì gẹ́gẹ́ bí igi owó pàtàkì kan láwùjọ Yorùbá. Aṣọ híhun jẹ́ iṣẹ́ kan tí àwọn obìnrin yàn láàyò ní ìlú wa. Mo mọ̀ bẹ́ẹ̀, pé o ti lọ sí Ìkòròdú. Gẹ́gẹ́ bí ifá yìí ṣe ṣàlàyé, ire lojú owó ń rí. Kí ni ìdí pàtàkì tó fi yẹ kí a kọ́ ilé yìí? Igbó lótun lósì, àwọn ilẹ̀ náà yóò wúlò fún ìjọba lọ́jọ́ iwájú, àbí kí lẹ rọ̀? Ìyá àgbà ti s’olóògbé. Mo máa bọ́’lè ní oríta-mẹ́rin yẹn o, ẹ jọ̀wọ́ ẹ rọra tẹná mọ́’kọ̀. Ìmọ̀ ti fi yé wa pé Òrìṣa Ògún ni àwọn alágbẹ̀dẹ. Ìjọ mà ń jẹyọ̀ nínú rẹ̀. Ìgbà tí Olùwa rẹ̀ dé ni Fadérẹra dákẹ́. Alábòsí ni wọ́n, àfàìmọ̀ kí ìṣe burúkú náà má bá wọn dàgbà. Wọ́n máa ń ṣe orò fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ j’̣ọba. Jẹ́ ka jẹ ègbo àti ẹ̀wà. Wàhálà tí àwọn ènìyàn ṣe láti lè jẹ́ ènìyàn láyé kìí ṣe kèrémí o. Kìí ṣe gbogbo ènìyàn ló mọ ìtumọ̀ orúkọ mi àfi àwọn tó ní ìmọ̀ tó jíire nípa orúkọ. Alhaji èyí ò dára tó, ó kù díẹ̀ káà tó. Èyí tí ó wá tún ṣe pàtàkì jùlọ ni wípé àwọn eniyan gbàgbọ́ pe ẹ̀mí ń bẹ lẹ́yìn ikú. Ṣé oṣó ni ẹ́ ni tàbí iwin? Ọmọkọ́mọ ni Dèjì. Ẹ máa sọ̀dí wùkẹ́wụ̀kẹ́. Ọmọ dada ni mí látijọ́. Tírélà náà ti dànù sí òpópónà Àpápá. Mo ṣèṣẹ̀ dé láti Califonia ni. Àsàwọ́ wà nínú oúnjẹ náà. Ọlọ́run nìkan ló mọ ohun tó ń ṣe fún àwọn ará ìlú. Yá mi ní gègé ìkọ̀wé rẹ. Màmá ni ki a máa fọ ẹsẹ̀ kí a tó bọ́ sórí ìbùsùn. Ìtan fèyíkọ́gbọ́n ni eléyìí fún gbogbo ẹ̀dá Ádámọ̀. Orúkọ ṣe pàtàkì, ó ṣe kókó; kò sí nǹkan tí a dá tí kò ní orúkọ. Àdùkẹ́ ń ta Mọ́sà ní àdúgbò kan ní Olúwọlé. Òdòdó kan ni a wá já n’ílée yín. Túndé sọ pé kábíyèsí wá sí ibi òde náà. Ayọ̀mídé ti rí’ṣẹ́ sí ìlú ọba. Balùwẹ̀ ni mo bọ́ sí tí mo ti ń jó. Gba owó yìí kí o fi jẹun àárọ̀. Egúngún náà ni Yorùbá máa ń pè ní ará ọ̀run. Faransé ló gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé bọ́ọ̀lù ní ọdùn tó kọjá. Olúwa, má ṣe ìgbọràn. Àánú ni mo tọrọ. Omi tí mo fẹ́ mu wà nínu kòkò irin. Ọdún egúngún yóò bẹ̀rè láìpẹ́. Ó ja ọbẹ̀ sí aṣọ. Kọ́bọ́ọ̀dù rẹ̀ ti bàjẹ́. Ẹni tó lówó layé yẹ. Àmì ayò mẹ́ta sí méjì ni Sàlámì fi na Sàláwà. Mo sọ fún Ajírébi pé tí ó bá ti ráyè kí ó wá kí mi nílé. Kòsọ́kọ́ ni àbígbẹ̀yìn bàbá tìrẹ. Ilé ti sú mi, ibo ni a lè lọ? T’akọ t’abo la dálé ayé. Ọkọ̀ náà ti bàjẹ́. Mo rántí ijọ́ tí ọmọ náà na ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pa. Igi gogoro ni wọ́n gé. Akíntúndé ti ṣètò gbogbo ìwé ìrìn àjò mi. Ọmọ́yẹlẹ́ ti yọ fáìlì náà kúrò ní ibi tí a kóo sí. Àṣá gbé ọmọ adìẹ fò lọ. Ibi ìjà kan ní kétu ni wọ́n ti fọ́ ojú ọmọ náà. Ogun ni ìlú yìí wà ní òní bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń fẹ́ kí gbogbo ayé rò pé àlááfíà ni. Bíbíire, Tìmílẹ́yìn àti Ṣẹ́gun jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Òkè àjà la gbée sí. Akéré fi inú ṣe ọgbọ́n ni wọ́n ń pèé. Òkè gíga pọ̀ ní àdúgbò yín. Akíntópé kìí ṣẹgbẹ́ẹ Ọládíji rárá. Àbá ni ikán ń dá, ikán ò le j’òkuta. Kìí ṣe awọn ọmọlóòkú nìkan ni o ti ṣe ní àǹfàní tipẹ́tipẹ́. Akokoro ló múu l’ẹ́yin. Bí ọmọ yìí ṣe máa ń sọ̀rọ̀ máa ń múmi lọ́kàn. Ẹ ṣe kíákíá kí a má baà pẹ́ dé. Kí wa ló tún kù tí ìyá Bọ̀dé ń wá káàkiri báyìí? Fálànà jẹ́ ògbóǹtarìgì agbejọ́rò àgbà ní orílẹ̀ èdè yìí. Gbogbo wa ni ọ̀rọ̀ yìí kàn. Akálolo ni Bídèmí nígbà tí ó ṣì kéré ṣùgbọ́n ó ti yàtọ̀ díẹ̀ ní sìnyí. Mo kórira irọ́ láyé mi. Wọ́n ni ilè àwọn Jẹ̀mílá l’àwọ́n wà. Ìwé mẹ́rin ni ọ̀gbẹ́ni Caleb ní ka rà. Atọ̀ọ́lé ni ọmọ náà. Àkìtàn ni gbogbo àdúgbò náà ní ayé ìgbà kan. Èdè ni ọ̀nà ìgbà báni-sọ̀rọ̀, èyí tí a fi ń gbé èrò-ọkàn wa jáde. Ní àkótán ìwúrí láti ẹnu àwọn àgbà dára púpọ̀. Àwọn gangan ni àpẹ̀ẹ̀rẹ̀ ọ̀rẹ́ kítíkítí àti ìyékan kàtàkàtà. Ọtí ẹlérin dòdò ni wọ́n fi ṣe mí lálejò ní’bi òde ìyàwó tí mo lọ. Eṣinṣín wá tìlẹ̀kùn ṣáláńgá mọ́rí, ó l’óun ò ní jáde àf’ìgbà tí wọ́n bá fún-un níyàwó. Ilà gọ̀m̀bọ̀ ni Tìmílẹ́yìn kọ. Jẹ́ ká jọ jó. Adémọ́lá nìkan ni ẹni tó mọ̀ ẹ̀dùn ọkàn mi. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú yẹn ná? Ṣé o ti jẹ ẹran ajá rí. Ọbabìrin Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti pẹ́ lórí oyè gan ò. Aláriwo ọmọ ni ẹ́. Ó ní èyí tóun mú lọ́wọ́ yìí ńkọ́, ṣé k’óun fi sílẹ̀ ni? Ó ti tóbi jù, mí ò lè gbée. Adébánjọ fẹ́ran ẹja tútù láti jẹ. Ní ọjọ́ kan, o múra oko dé, pẹ̀lú ìhámọ́ra. Ẹ́sítérì máa ń hùwà òmùgọ̀. Kí a ní ìyàwó tó rẹwà kò ṣe pàtàkí tó èyí tó n’íwà. Àlùfáà ń wàásù fún àwọn ọmọ ìjọ. Iṣẹ́ atọ́kọ̀ṣe ni Kọ̀tún kọ́. Agbọ́n ta Ṣubúọ́lá. Mo bẹ̀rù olóńgbò púpọ̀. Ilé títúnṣe àti ọmọ títọ́ ni iṣẹ́ ti àwọn ìyá nígbà yẹn. Bí ènìyàn ṣe ń lo èdè bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹrankọ ní bí wọ́n ṣe máa ń bára wọn sọ̀rọ̀. Wá rí mi, mo ní ǹkan tí mo fẹ́ fún ẹ. Ìmọ́tótó borí ààrùn mọ́lẹ̀ bí ọyẹ́ ṣe ń borí ooru. Àlùbọ́sà ni ó ń tà. Oúnjẹ náà ti rà. Wọ́n gbàgbọ́ pé iṣẹ́ tí àwọn fi orúkọ náà rán sí ọmọ bẹ́ẹ̀ yóò kó ipa ribiribi. Ọmọ yẹn ò lẹ́kọ̀ọ́. Ilé ìwòsàn ní Ládòkè ti padà rí ẹni tí ó ń wá. Mo fẹ́ dá ilé iṣẹ́ atẹ̀wé ìròyìn sílẹ̀. Ó ti padà dé láti òkè òkun. Bẹ́ẹ̀ àṣejù wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ níkẹyìn. Oò sì ní ṣ’aláì bímọ. Olówó ló layé ni wọ́n máa ń wí. Gbogbo àwọn ọmọ tó bí ti kú mọ́ọ lójú. Kò sí bí èèyàn kan ṣe le kàwé tó, kò lè mọ gbogbo ǹkan tán nílé ayé. Ní ìgbà láíláí, ọ̀rẹ́ ni ìjàpá àti àdàbà jẹ́ sí ara wọn. Ọ̀dẹ̀ burúkú l’ọmọ Ajíbóyè yìí tó dá mi dúró. Ẹ̀fọ́rí ló kọ lùú. Alágbára ọdẹ ni bàbá náà. Etí rẹ̀ pẹ̀lú a sì máa gbọ́ ìgbọ́kùgbọ̀ọ́. Adétọ́lá wà ní ilé ìwé gíga. Ẹ̀rọ ayárabíàṣá ni mo fi ṣe iṣẹ́ náà. Ẹ kú ọjọ́ ìbí ooo, ọ̀jọ̀gbọ́n Ṣóyínká. Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé girama ni Ọládiípọ̀. Ìjàm̀bá ọkọ̀ òfurufú tó ṣẹlẹ̀ níjọ́sí ò tíì lọ lórí àwọn ènìyàn. Ẹ̀ṣọ́ dára fún ara. Alákọrí ni Àkànbí tó k’àkànpọ̀ nínú ooru. Iké màlú náà tóbi. Olúwa, má jẹ ka pàdánù. Gbà gbà gbà lọkọ̀ ń dún lóríi títì. Ó ti rẹ̀ wá púpọ̀. Pẹ̀lúmi pè mí láti dúpẹ́ oore. Lọ wẹ̀ kí o yé rùn. Ìyàwó ẹlẹ́sẹ̀ osùn, rọra máa wolẹ̀. Níbi tí mo rìnriǹ àjò lọ, ará oko gbáà ni wọ́n. Wọn-òn dá ohun kan mọ̀. Ẹ̀mí á ṣe púpọ̀ ọdún láyé. Ilẹ̀ẹ ta lèyí? Ìya oní gaàrí ti ń bọ̀. Adìẹ ti yé ẹyin sílẹ̀. Àwọn ohun amáyédẹ̀rún ti pọ̀ lóde. Ìréde òru ti àwọn ọ̀dọ́mọgé ìsíyìín rawọ́ lé mà ti wá peléke. Ṣé pé a lè dolówó dọlọ́rọ̀ látara gbíngbin igi obì. Aláfẹ́ ni bọ̀dá Ládi. O fẹ́ bá ọmọ yẹn sùn àbí bẹ́ẹ̀ kọ́ ni? Àbẹ̀kẹ́ ti kiri àgbàdo lọ. Adéforítì ní ìforítì. Tùràrí olóòórùn dídùn ni wọ́n fi sí ibi ìtẹ́ òkú. Ikún wà ní imú rẹ. Láfihàn ló gba àmì ẹ̀yẹ Ọba. Ìgbàyí ni ọlá mi tó kún. Àná ò le jọ t’òní, tòní ò sì jọ t’ọ̀la. Akọ ń lé ‘rin, abo ń gbè é. Wọ́n fẹ́ràn láti máa jẹ àkàrà. Kí ló dé tí o wà nínú àhámọ́. Ẹ̀yin ará ẹ jọ̀wọ́, ìwé ìdánimọ̀ mi àtẹ̀yìnwá ní àwọn ìṣọ̀rọ̀ kan. Adéẹ̀kọ́ ní òun nífẹ̀ẹ́ omí jù ó ti lọ. Àgbàlagbà ara lọ́ fi bí’mọ. Ó gbe ọmọ rẹ̀ wá kí mi ní’lé. Bíyi ti padà sí Èbúté Mẹ́ta. Ó dá mi lójú pé mo mọ iṣẹ́ náà ṣe. Túndé ti lọ gẹ’run ẹ̀. Akọ́lédowó ti kọ́lẹ́ alájà méje. Kílàsì àkọ́kọ́ ni a ti kọ́ nípa Fonọ́lọ́jì. Kí Ọlọ́run má fi oúnjẹ wa síbi tó nira. Ìró wà ní orí ilẹ̀kùn. Ta ló tẹ ìlù yìí dó? Àwọn ohun èlò akọrin ni ìlù, fèrè, jìtá, àti agogo. Ẹ má lọ sínú igbó lóru o. Òkè pọ̀ ní Ìṣẹ̀yìn ju Ọ̀yọ́ lọ. Ẹsẹ̀ ń ro mí ooo, ta ló rán mi n’íṣẹ bọ́ọ́lù gbígbá. Ẹ̀wọ̀n gbére ni wọ́n ju ọ̀daràn náà sí. Moróunkẹ́ fọ́ ọkàn mi sí wẹ́wẹ́. Kò sí bí òǹkọ̀wé Yorùbá ṣe fẹ́ tẹ̀lé òfin àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ. Ìjàkùmọ̀ kìí rìnde ọ̀sán. Mi ò lè dé mọ́ lónìí, torí àwọn ọ̀rẹ́ méji yìí ti bá mi jà. Inú ilé ni mo bá ìyàwó kékeré tí wọ́n fẹ́ fún bàbá. Ó yẹ kí n yọjú síi yín láìpẹ́. Kí màmá tó lọ sọ́jà ló ti sọ fún mi kí n pàrọ̀ aṣọ àbúrò mi. Àwọn Ọmọ náà fẹ́ kọ́ èdè Yorùbá. Bí a ṣe ń gbà ó nínú wàhálà kan lo ń bọ́ sí òmíràn. Èyí ni ó mú wa fi òwe wá àwọn oun tó sọnù sínú ọ̀rọ̀ Yorùbá. Àdùké àti Adémọ́lá ni àbúrò Bánkẹ́. Ṣọ̀pọ̀ná ò ní mọ ‘lé wa o. Àmin. Ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ ni àwọn Táyọ̀ Ohun tí Ajétúnmọbí fún mi ni mo dà kọ. Ṣé ki n wá gba kiníyẹn ni? Irú àṣìtẹ̀ burúkú wo ni èyí? Mi ò nífẹ kí n máa bẹ̀bẹ̀, ìdí nìyí tí mo máa fi ń gbìyànjú láti má t’asẹ̀ àgẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí ẹ́nikẹ́ni. Mo fẹ́ mu àgbo jẹ̀díjẹ̀dí. Àwámárììdí ni ọlọ́run. Agbẹjọ́rò ní kí o wá sínú yàrá ìgbẹ́jọ́ láti wá jẹun. Awólọ́wọ̀ ṣe díẹ̀ nínú ètò òṣèlù orílẹ̀ èdè yìí. Jalabíà dúdú ni mo wọ̀ lọ kí ìrun yídì ní ọjọ́ ọdún. Ní àná, ò ń wò bí ẹyẹ t’ójò pa. Òkè ni ẹyẹ ti máa ń fò. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ni wọ́n kọ́ mi bí wọ́n ṣe máa ń se oúnjẹ. Erín tóbi ju ajá lọ. Ṣ’ara gírí kí o lo àwọn ògùn tí Dókítà kọ fún ẹ. A máa lọ gba ilé sí Àkóbọ̀. Lọ ra èlùbọ́ wa lọ́dọ Ìya Mọ́ríá. Àwọn ará ọjà ti kó aṣọ lọ. Èkúté náà ti jẹ gbogbo ẹja inú ìṣasùn. Àgbà ò ní tán lórílẹ̀. Iṣẹ́ àmúrelé tí olùkọ́ àgbà fún wa yìí le gan o. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọdé fẹ́ràn patí. O ṣé pàtàkì púpọ̀ kí n báa jẹun. Bàtà náà rẹwà l’ẹ́sẹ̀ rẹ̀. Ṣé bí à ṣe dúdú náà ni ọpọlọ wa ṣe dúdú ni? Súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ pọ̀ ní ọ̀nà Ìkòròdú. Ọkọ̀ akérò ni mo wọ̀. Èsì ìdánwò fún sáà yí dára púpọ̀ jọjọ. Ìgbín jẹ́ ẹranko kan tí ó nífẹ láti máa sìn. Gbogbo ìgbìyànjú mi ò gbọdọ̀ já s’ásán. Tí mo bá ní mi ò rin ìrìn àjò báyi rí, irọ́ ni mo pa. Ohun tí ó dára ni láti wà pẹ̀lú enìkan tì èèyàn fẹ́ràn. Ìrìn àjò láti Èkó sí Ìbàdàn tó wákàtí méjì ààbọ̀. Irú èyí ò lè ṣẹlẹ̀ ní’lu òkè rárá. Ayé dùn-ún jẹ jùyà lọ ni ọ̀rọ̀ tó bọ́ lẹ́nu Ṣùbòmí nígbà tó jẹ àmàlà tán. Àlùfáà tuntun tí a gbé wá ni ó ni aṣọ náà. Ọmọ yìí fẹ́ fi ijó ṣe mí léṣe. Ọdẹ adẹdò ni Ọdẹ́wálé jẹ́ nígbà èwe rẹ̀. Ṣé ó dẹ̀ ma yó báyìí? Ọ̀gá ọlọ́pàá ni Bàba Kúdí. Ó f’ọwọ́ lérán ó ń wò’ṣe olúwa. Ògo ọmọ náà tàn kálẹ̀. Mo wá ṣe bí àdán orí igi tó so ara rẹ̀ rọ̀ bí ẹni tó ń tòògbé. Iná gbé Adétiba nígbà tó fọwọ́ kan òpó iná. Bọ́lá máa ń ṣe ìrànrán tí kò bá tètè sùn. Báwo ni ọmọ ogójì ọdún ṣe máa fẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún? Nígbà mìíràn, tí ìfẹ́ bá pọ̀jù, kò dára. Dígí tí a gbé sí balùwẹ̀ ti fọ́ ní àná. Àti ìjẹ́rin la ti ri’ra gbẹ̀yin. Mo gbádùn eré náà dáadáa láti ìjẹta. Aṣọ títà ni iṣẹ́ ìya Bùkọ́lá. Màmá mi ṣẹ̀ṣẹ se ọbẹ̀ mìíràn ni. Ìbẹ́pẹ náà pọ̀n púpọ̀. Ibo ni kí n fi fìlà yìí sí? Ayé là á jẹ, ka tó jọ̀run. Miò kí n fi bẹ́ẹ̀ ṣeré níta. Ire ló yẹ ní ṣíṣe, ìkà kọ́. Mo nífẹ màmá mi. Mo nílò láti ra àwọn èwù tuntun. Igi náà rí ràbàtà. Bí èkùrọ́ ṣe jẹ́ alábákú ẹ̀wà bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ mi sí o. Mo fẹ́ rán ọmọ méjì ní’ṣẹ́. O kú àdúrótì mi. Gbogbo yàra ti sùn lọ. Mo fẹ́ lọ sí ọdún Ọ̀ṣun Òṣogbo. Ẹ máa gbọ́ o, kẹ́ẹ bá wa dá síi. Ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run ni ó wà. Ó ra ọtí fún wa, ẹ bá wa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Áà! inú òjò l’àwọn omọ yí ti ń ṣeré. Ìtara mú adájọ́ náà. Nínú ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá tí wọ́n dá fún Tájù, ọdún mẹ́wàá ló lò níbẹ̀. Ipin máa ń wà l’ójú ajá náà ní gbogbo ìgbà. Mo fẹ́ ra oògùn. Pìrìgìdì ìyà ni wàá jẹ kúrò nídiìi ayò yìí lónìí. A tiẹ̀ ríi gbọ́ pé ilé alájà mẹ́ta ni bàbá yìí kọ́ sí ìlú rẹ̀. Báàgì tuntun ni Titó gbé wá sí ode àríyá náà. Ìjàpá gbọ́n gan ni nínú àwọn ìtàn Yorùbá. Adéyinká sọ pé òun ò lè jẹ́ kí ẹnikan máa ku akoko òun danù bíi èlùbọ́. Agbejọ́rò náà kú l’ówurọ̀ yìí. A gbé òṣùbà fún iṣẹ́ ńlá tí àwọn bàbá wá ṣe sí ìletò yìí. Ikú á pa babaláwo bí ẹni tí ò gbọ́fá rí. Inú ń ro mí o. Mo rántí ìgbà èwe mi àti àwọn oun tí mo ṣe. Kí ló dé tí ojú rẹ k’ọ́rẹ́ lọ́wọ́? Ọ̀rẹ́ mi Adisa fẹ́ràn eẹ̀yan púpọ̀. Àwọn Àńjọlá yóò dé láti Amẹ́ríkà láìpẹ́. Fún mi ní aṣọ yìí, mo ní’fẹ rẹ̀. Ṣé ẹranko ni ikún ni? Olúwa ọlọ́run, ọba atẹ́rere kárí ayé. Ọmọ yìí gọ̀ gan, kò tiẹ̀ mọ̀ èèyàn-án kí. Mi ò tiẹ̀ mọ ìlú tí ó ní òkè jù láàárín Ìsẹ́yìn àti Oǹdó. Mo gba ìpè láti ọ̀dọ̀ olólùfẹ́ mi, ó ní òun fẹ́ wá kí mi nílé. Àwọn bíríkìlà ń tún ilé náà ṣe. Ìjà náà bẹ́ sílẹ̀ nìgbà tí awakọ̀ kọ̀ láti wa ọkọ rẹ̀ kúrò lójúu pópó. Ilé olórogún ni ó ti wá. Òjo pa wá dé ìbàdàn ni níjọ́ náà. Ibo lẹ fi ọ̀bẹ sí? A jeun nínú àwo kanáà fún ìgbà àkọ́kọ́. Aṣá ló lọ gbé ọmọ adìyẹ lórí ibẹ̀. Gbogbo ọmọ ìyá ìbejì ló ti bí’mọ. Nígbà tí bàbá lọ sí oko ní ijọ́ kan ló rí ọmọ ìkókó náà ní abẹ́ igi ọsàn. Ẹlẹ́pà ìjẹ̀bú — èyí tí o fẹ́rà gaan — wà ní ìtòsí. Irun dúdú ni kìkì gbogbo ara olóńgbò náà. Jẹ́ kí ó ṣe bí ó bá ṣe fẹ́. Ìdí ọkọ̀ ni mo gbé ẹrù lọ ní àná nígbà tí ọkọ̀ gbá ajá àwọn màmá. Abúlé wọn tóbi gan. Asọ̀rọ̀ sọ bótò ni Kòfowórọlá. Mo túbá fún gbogbo àṣìṣe tí mo ti ṣe s’ẹ́yìn. Wọ́n n bá ara wọn sọ̀rọ̀ lówelówe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ni wọ́n ma ń bá ìyá wọn rẹ́ ṣùgbọ́n báyi kọ́ lọ̀rọ̀ rí fún Jayé. Ọmọ yìí fi ewúrẹ́ rúbọ bí babalawo ti sọ fún un. Mi ò tíì mọ oun tí mo máa jẹ lónìí. Kí ló dé ti ò kìí kan ilẹ̀kùn? Irú ìbéèrè wo lèyí? Alákadá ni ọ̀gá rẹ̀. Mo gbá bọ́ọ̀lù wọ’nú àwọ̀n fún ìgbà àkọ́kọ́. Ẹ̀sin mùsùlùmí ò fàyè sílẹ̀ fún ajá jíjẹ. Onígèlè yaya ni màmá yẹn. Ẹ máa sọ̀rọ̀ yín lọ. Àwa la ó máa wá, ẹ̀yin la ó máa bá. Alágídí l’ọmọ náà, ó fi jọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ni. Isaiah àti Arógunyọ̀ ń fẹ́ obìnrin kannáà. Mo fẹ́ mu àgbo jẹ̀díjẹ̀dí. Ìyá àgbà fi ògùsọ̀ dáná. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ olúwa fún gbogbo iṣẹ́ rere rẹ̀. A jeun nínú àwo kanáà fún ìgbà àkọ́kọ́. Bí àwọn dókítà mìíràn ṣe máa ń bá’ni sọ̀rọ̀ kò daa rárá. Mo ti sùn lé ọrùn mi. Iṣan apá rẹ̀ ti já. Ta ló ń lọ fún ìdíje náà? Ẹni tó bá lówó lọ́wọ́ kó ṣe bí ẹni tí ò ní. Koríko ni ewúré máa ń jẹ. Ó fi ipá báa lò pọ̀ lánàá. Ìfẹ́ wá mi wá sílé ṣùgbọ́n mo ti lọ ìrìn àjò nígbà náà. Iṣẹ́ atọ́kóṣẹ̀ ni Kòtún kọ́. Mo rántí ijọ́ tí ọmọ náà na ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pa. Ṣé kò f’ara pa púpọ̀? Ṣé mò ti ṣe oun tí o fẹ́? Akọ̀wé Ẹgbẹ́ ni Tẹ̀là. Jẹ kin sìn ọ́ dé ojú ọ̀nà díẹ̀. Kúnlé ti lọ ra àgádàgodo wá. Ọlọ́runyọmí ló tan Ìwàlọlá jẹ. Mo ò tí ì dé Àbújá rí. Ẹniafẹ́ ti parí ilé ìwé gíga. Iṣẹ́ ìran dé ìran ni iṣẹ́ ọdẹ́ jẹ́. Ìfẹ́lódùn lorúkọ ẹgbẹ́ náà. Èdùmàrè á fún mi l’áya rere. Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé girama ni Ọládiípọ̀. Tàlàbí ti ga jù. Àwọn ènìyàn kìí sábà fi àrò dáná mọ́. Ikú gbígbóná ni Ikú tí Akíntọ́lá kú. Ká má tètè kú lawo ìbànújẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọdé fẹ́ràn patí. Gbogbo ara ni mo fi kí ẹ jàre, àbúrò mi. Ojú mi rí kí n tó ni gbogbo dúkìá yìí. Ẹ fi ṣàkì mẹ́ta sórí ìrẹsì àkọ́kọ́. Ìrẹsì àti ẹja ni èmi àti Élújọbí jẹ ní òwúrọ òní. Ẹsẹ̀ àga náà ti kạ́n. Mò ń lọ sí ilé Ìya Ṣọlá. Kí lẹ ṣe ní kílàsì lénìí? Ọgbà àjárá ni ó yí ilé náà ká. Ilé ìjọsìn wa ni tósìn ti kọ́ dùrù títẹ̀. Ìjà bẹ́ sílè láàárín Pópóọlá àti Àlùfá mọ́sálásí wọn. Olú Owólabí ló ko Ìwé ìtàn-àròsọ Ìjà Ọ̀rẹ̀. Ìyá àgbà ti s’olóògbé. Bí ọmọ yìí ṣe máa ń sọ̀rọ̀ máa ń múmi lọ́kàn. Ọ̀jọ̀gbọ́n sàlàyé lórí rògbòdìyàn tó bẹ́ sílẹ̀ ní ìlú ọba ní àná òde yìí. Tí ọwọ́ rẹ́ bá kàn mí, mo ma yí omi yìí dà sí ẹ lórí. Ohun gidi kọ́ ni k’éyàn bá ogun lọ. A gbọ́ pé wọ́n ti jí ẹní egbére lọ. Nígbà tí ènìyàn tó burú báyìí bá ń ronú kó jáwọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́, mélòómélòó ìwọ. Àwọn aṣọ híhun náà rẹwà púpọ̀. Wàhálà rẹ pòjù, Àdùnní. Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ẹ? A tiẹ̀ ríi gbọ́ pé ilé alájà mẹ́ta ni bàbá yíì kọ́ sí ìlú rẹ̀. Òyìnbó bí ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ́ ni ó máa ń sọ ní tirẹ̀. Bákan náà ẹwẹ̀, àkíyesí tùn wà pé, àwọn okùnrin ni ó pò jù nídìí iṣẹ́ orin. Túndé jẹ mí ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà. Wọ́n ti fi Akínsọ̀yínù sínú túbú. Ibo ni kí n fi fìlà yìí sí? Etí ń rìn mí ṣá. Ọmọ ọkùnrin yẹn da èkan náà sí. Nínú yàrá náà, ènìyàn márùn-ún ló ń sùn síbẹ̀. Ọ̀rẹ́ làwọn máràrùn. Kí Ajíjọlá wọlé kí á jọ ṣeré. Mo máa ń lérò pé Bélò ní ọpọlọ ni o, àṣé orí rẹ̀ ò pé rárá. Orin dàdàkùádà máa ń ní ìlù lílù, ijó jíjó, ẹfẹ̀ ṣís̀e, àti oríkì. Wọ́n dáná sí ẹ̀gbẹ́ igbó. Èmi náà fẹ́ ní ọ̀rẹ́bìrin nílé. Gbogbo aṣọ kọ́ la ń sá lóòrùn. Onílẹ̀ gogoro ni wọ́n ń pe ọkùnrin yẹn. Gbogbo abọ́ ló ti dọ̀tí. Mo ò tíì ri irú erin tó tóbi báyìí rí. Ẹni tó ti kú ò ní ìrèti mọ́. Ìkọ̀tún ni ibi tí àwọn ayálégbé wa tẹ́lẹ̀ ń gbé báyìí. A rí kínǹiún ní ibi tí a ti lọ wo àwọn ẹranko. Òkè gíga pọ̀ ní àdúgbò yín. Yá mi ní gègé ìkọ̀wé rẹ. Adésuà mọ bí yóò ṣe bá wa mú orí rẹ̀ wá’lẹ̀. Tí mo bá pè ẹ́, máa dá mi lóhùn. Àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nìjíríà ní àfojúsùn láti gba ife ẹ̀yẹ ti ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú tó ń lọ lọ́wọ́. Bọ̀dá táyé ti lọ sí Mecca ní ọdún tó kọjá. Gbogbo aṣọ kọ́ là ń sá lóòrùn. Alágbára òde ni bàbá náà. Kì ń ṣe gbogbo nǹkan lèyàn ń dá sí. Mo fẹ́ mu gaàrí àti ẹ̀pà. Mo fẹ́ ra ọtí fún Ìya Sùlíyá. Adébánjọ fẹ́ran ẹja tútù láti jẹ. Ó ní èyí tóun mú lọ́wọ́ yìí ńkọ́, ṣé k’óun fi sílẹ̀ ni? Ọmọ náà fẹ́ràn láti ma wò mí. Bàbá àgbà ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún. Tẹ̀là ló jẹ́ kí gbogbo ọ̀rọ̀ yí lọ di òkòtó báyìí. Ìsọkúsọ ni Àdèlé ma ń sọ ní gbogbo ìgbà. Kìí ṣe dúndùn inú ẹnikẹ́ni kí ọmọ rẹ́ kú. Òkun kìí gùn jù ká má mọ ibi tó ti gùn wá. Àtòrì ńlá ni wọ́n fi nàá. Ta ló gbé ẹ̀fọ́ tí mo gbé wọlé. Ẹgbọ́n rẹ̀ ni ó rẹ̀ẹ́ lẹ́kún. Ọmọ ìya ológì lókè Mẹ̀sàán ni mí. Òtútù ń mú ọmọ tí ń sọ ìkan fún mi yí, níṣe ló ká jọ bí i adìẹ tí òjo pa. Àwọn wo ló ń pariwo láàárọ̀ kùtùkùtù báyìí. Láfihàn ló gba àmì ẹ̀yẹ Ọba. Àjásin kò rántí gbé ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán fún ẹni tó ń tun-un ṣe. Ìya oní gaàrí ti ń bọ̀. Ọbá ti wàjà nílú Àkúrẹ́. Ta ló gbé omi tí mo pọn? Gbẹ́nu sọ́un, oní’bèérè ìsọlẹ́nu. Ìsọkúsọ àwọn mìíràn pọ̀ jù. Oúnjẹ náà ti rà. O fẹ́ bá ọmọ yẹn sùn àbí bẹ́ẹ̀ kọ́ ni? Bíyi ti padà sí Èbúté Mẹ́ta. Àgbélébú mi ni mo gbé rù lọ́wọ́lọ́wọ́. Oko àlùbọ́sà ni mo rà. Tírélà náà ti dànù sí òpópónà Àpápá. Adétọ́lá wà ní ilé ìwé gíga. Àwọn ará ọjà ti kó aṣọ lọ. Ìdí ni wípé èdè pọ̀ láwùjọ jáńtìrẹrẹ. Ǹjẹ́ ó ṣeéṣe kí Àrólé pa ọ̀rẹ́ rè? Dáníẹ̀lì wọ bàtàa dùbúlẹ̀. Mo fẹ́ lọ gbafẹ́ l’ágbo fújì. Ẹranko burúkú kan ló pa àwọn ẹran náà jẹ. Ìjẹ̀bú ni bàbá ọmọ náà ti máa ń wá. Ṣé ki n gbé oúnjẹ rẹ lọ fún-un? Ọ̀rẹ́ mi Adisa fẹ́ràn eẹ̀yan púpọ̀. Ó ti wá hàn gbangba gbàǹgbà pé ọ̀pọ̀ ohun tí à ń ṣe ni àwon ara ìlú fẹ́. Bàtà náà rẹwà l’ẹ́sẹ̀ rẹ̀. Àwọn ọsàn náà ti pọ́n. Ní ìgbà kan rí kò tilẹ̀ ní lítíréṣọ̀ àpinlẹ̀kọ rárá débi pé wọ́n á ní ìwé ìtàn àrósọ. Ibo ni fàájì wà lálẹ́ òní? Àwọn Ọḷ́opàá ya wo àdúgbò tí ìjà ti bẹ́ sí’lẹ̀. Ganíyá fẹ́ràn kí ó ma tọ́’jà kiri. Lọ fi aṣọ bo omi mímu yẹn. Omi yẹn ti tùtù ju fún mi. Ilé wa ò ní dàrú, ọ̀nà wa ò ní bàjẹ́. Èyàn mẹ́fà ló ń jẹ́ Máíkẹ̀lì ní kílàsì wa. Ìró wà ní orí ilẹ̀kùn. Mi ò ní tó iye owó yìí. Ó gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Afọpẹ́fólúwa ní ìdodo ńlá. Ọdún Ifá jẹ́ ọdún kan pàtàkì tí a fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè. Túndé ní’fẹ sí àti máa fi ẹ̀wà jẹ ọ̀gọ̀dẹ̀. Ó gbe ọmọ rẹ̀ wá kí mi ní’lé. Akànlé ni bàba Àìná ń ṣe bí iṣẹ́. Kí ọmọ olówó má ro ọmọ tálákà pin. Àrá ló ya ògiri yí lulẹ̀. Wọ́n ni ilè àwọn Jẹ̀mílá l’àwọ́n wà. Wá rí mi, mo ní ǹkan tí mo fẹ́ fún ẹ. Òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ amúnáwá náà gan mọ́ orí òpó. Aṣọ funfun àti fìlà olómi aró ni wọ́n pè. Ìgà ni wọ́n ń pe Àfin ní Èkó. Mo gbádùn eré náà dáadáa láti ìjẹta. Ìdìbò tí ń bọ̀ lọ́nà ló fa gbogbo gbómi si omi ò tóo. Mo fẹ́ ra oògùn. Ọ̀nà ibo ni mo lè gbà dé Sáfẹ́jọ́? Àlùfáà tuntun tí a gbé wá ni ó ni aṣọ náà. Ifálékè ti j’Ọba o. Ọjọ́ àbámẹ́ta nìkan ni mo máa ma lọ sí ibiiṣẹ́. Ẹ ṣùpọ̀ sójú kan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ bọ̀gìnì bọ̀gìnì ni mo rí lóju pópó nígbà ìrìn àjò náà. Òru ni àwọn àjẹ́ máa ń ṣe ìpàdé. Ìyàwó kékeré tí arákùnrin òhún fẹ́ ló ba gbogbo nǹkan jẹ́. Wọ́n ní ká dá owó fún ọmọ tí ó rẹ̀. Ọkọ́ àti àdá jẹ́ ohun èlò gbòógì fún àwọn àgbẹ̀. Àṣàkẹ́ ti lọ p’ọmi ní odò tí ó súnmọ́ Modákẹ́kẹ́. Ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi ti sọnù. Hohùn dídùn ni wọ́n fi ń kí’fá. Kò sí ẹni tí kò lè dáa fún. Iṣẹ́ la fẹ́ ṣe, a kìí ṣ’ọ̀lẹ. Mo ní àǹfààní láti dé Adó Àwáyè. Sọ fún bàba ọlọ́kọ̀ kó lọ gbé àwọn èrò tó wà ní ibùsọ̀ lọ́un yẹn. Mo fẹ́ kí èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi jọ ma lọ sí ibẹ̀ nígbà kan náà. Àbíkú l’ọmọ yẹ́n jẹ́. Irú irun wo lo wá gẹ̀ s’órí báyi? Mo ti lo rí ọ̀gá mi kan lorí ọ̀rọ̀ ọ̀hún. Jẹ́ ka jẹ ègbo àti ẹ̀wà. Ṣe ìlérí fún mi pé ò ní fi mí sílẹ̀. Òkédìjí ló sọ bẹ́ẹ̀ nínú ìkan lára àwọn ìwé ẹ̀. Orí òkè náà ga gidi gan. Ta ló mọ̀ ẹ́? Ìṣe ẹni ní ń sọni dẹni gíga. Wón ní kí a wá gba ẹran ọdún. Ẹ wá ra bèbí fún mi. Àwọn pẹ́pẹ́yẹ ń wẹ̀ nínú odò. Ṣoò lè jáde kúrò nínu yàrá mi. Egbére jẹ́ ẹ̀yà iwin kan. Iléèwé náà tóbi púpọ̀, ogunlọ́gọ̀ ọmọ ni wọ́n ní. Aà jí ire bí, ẹ̀yin ọmọ Oòduà? Ta ló lágbára jù nínú iwin àti egbére. Kí la fẹ́ gbà nínú ìjà. O ṣé, mo dúpẹ́ pé ìgbàgbọ́ rẹ nínú mi ṣì múlẹ̀ ṣinṣin. Simisọ́lá lorúkọ ìyàwó Adékúnlé. Àwọn Àbẹ́gbẹ́ yóo tó dé láti Ísírẹ́lì ní ọ̀sẹ̀ méjì sí òní. Oṣù kan ààbọ̀ ni mo fi dáwó láti ra ọkọ̀ bọ̀gìnì náà. Akínwùnmí fẹ́ kọ́ bí wọ́n ṣe ń ka ewì. Kí ló dé tí ojú rẹ k’ọ́rẹ́ lọ́wọ́? Mo ní èróngbà láti gbé àpótí ìdìbò lọ́jọ́ kan. Alájàpá ni iṣẹ́ tí Lọlá ń ṣe kó tó wọ iṣẹ́ Ọlọ́pàá. Òkè àjá lẹ gbée sí. Ẹ gbé iléelẹ̀ yín wá fún àwọn agbálẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ó ti ṣẹ́yún yẹn. Ọ̀rọ̀ tí mo gbó já mi láyà púpọ̀. Àárẹ̀ náà ti wọ inú ara rẹ̀ tán. Ní àkótán ìwúrì láti ẹnu àwọn àgbà dára púpọ̀. Olúwa, má jẹ ka pàdánù. Ẹ̀san ń bẹ fún ẹni tó bá ṣẹ̀’ka. Ààfáà ń pè’run láago márùún. Ṣé o mọ Allen Avenue? Gbogbo ara ló ń wọ́ mi. À ń ṣiṣẹ́ kí a tó rówó ni. Ṣé o lè yá mi l’ówó títí di ìparí oṣù. Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni gbogbo wa, àbí? Àlùjó ni wọ́n ń lù lágbo Ayéfẹ́lẹ́. Kí Ọlọ́run jé kí orílẹ̀-èdè yí dára. Ògbójú ọdẹ ni wọ́n. Èékánná tí o lé sọ́wọ́ rẹwà púpò. Àfàìmọ̀ kí ọ̀rọ̀ rẹ́ má da gbogbo nǹkan rú. Ayẹyẹ náà yóò lárinrin yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Ọjọ́ ìbí mi ń bọ̀ lọ́nà. Iná ti tán lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi. Elétí kunkun ni Túndé. Ẹ̀kọ́ dára púpọ̀, òun sì jẹ́ ìkan lára oun tí a nílò láti di ẹni gíga l’áwùjọ. Afẹ́fẹ́ ń kọjálọ lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀, gbogbo ohun ń lo létòlétò. Mi ò tiẹ̀ mọ ìlú tí ó ní òkè jù láàárín Ìsẹ́yìn àti Òǹdó. Kò ye ká máa sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà torí a ò mọ ẹni tó lè ranni ĺọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ àṣejù wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ní ìkẹyìn. Ọyún ń yọ ní etí ẹ̀. Àwọn àgbà ló máa ń sọ pé ‘igúnnugún kìí kú léwe.’ Àwọn arẹwà obìnrin pọ̀ nílùú. Ohun rere ni yóò ma jẹ ti wa. Bàbá rẹ̀ ló fi ṣìná jọ. Ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ wa fẹ́ràn omi tútù. Mo fẹ́ dá ilé iṣẹ́ atẹ̀wé ìròyìn sílẹ̀. Olú sùn fọnfọn lóru. Ọtí àmupara ni Akínbọ̀dé mu ló bá ń sọ bótobòto ní òru àná. Ọgbọ́n ló gbà tó bá ti jẹ́ ọ̀rọ̀ obìnrin. Ajíbádé fẹ́ràn obìnrin púpọ̀. Màálù mi ti kú. Kí ló dé tí wọn ò ṣu orí fún ọmọ yìí? Iṣẹ́ ṣí pọ̀ nílẹ̀ táa fẹ́ ṣe. Ògo ọmọ náà tàn kálẹ̀. Ọba Moróunfólú ò pé lóri oyè rárá, odún mẹ́ta péré ló lò. Ajò ò le dùn bí ilé. Ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá ni ẹ̀sìn ìsìlámù. Àwámárììdí ni Olódùmarè. Wọ́n rò pé èmi ni mo sọ fún ẹ bẹ́ẹ̀. Láti orí dé orúnkún ni òógùn ti bòó nígbà tí a gbọ́ ohùn ìbọn tí àwọn ọ̀daràn náà yìn. Erín tóbi ju ajá lọ. Mi ò nífẹ kí n máa bẹ̀bẹ̀, ìdí nìyí tí mo fi ń gbìyànjú láti má t’asẹ̀ àgẹ̀ẹ̀rẹ̀ s’ẹ́nikẹ́ni. Àkàrà òyìnbó náà dúdú. Àlákála ni Adéníkẹ lá pẹ̀lú Ayaba Èṣítẹ̀rí. Fásúre jẹ́ ògbóǹtarìgì oníṣègùn ní agbègbè. O kú àdúrótì mi. Ṣé pé a lè dolówó dọlọ́rọ̀ látara gbíngbin igi obì. Ó ti tó lẹ̀. Ìrìn àjò láti Èkó sí Ìbàdàn tó wákàtí méjì ààbọ̀. Lọ já ewé efinrin wá. Láfún ni a jẹ. Ṣàngó gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe fi yé wa ni aláàfin kẹta ní ìlú Ọ̀yọ́. Kí lẹ fẹ́ kó, ṣé kí n bá ẹ kóo. Pọ́ọ̀lù ló bá mi wá iṣẹ́ náà. Ọ̀ṣínbájò ni igbákejì àrẹ orílẹ̀-èdè Nìgíríà. Kò bìkítà bóyá ó dára tàbí kò dára. Ipin máa ń wà l’ójú ajá náà ní gbogbo ìgbà. Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìdí ni a lè tọ́ka sí pé ó ṣokùnfà pípẹ́ lẹ́yìn ìwé ìtàn àròsọ Yòrùbá. Aṣọ kaánà ni t’ọko t’ìyàwó wọn wọ̀ lọ sí ilé ìjọsìn l’énìí. Ijọ́ ìgbéyàwó mi, ẹ ó ríran wò. Ọkunrin ńlá ni Bàba Sọlá tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ẹniọlá ni orúkọ Màma wọn. Ẹ jẹ́ ká lọ fọṣọ wa kó ba lè mọ́. Mo mọ bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ tí mo fi ń rówó. Àmọ̀pé ni wọ́n sọ ọmọ náà, bàbá Láfẹ́nwá ló fún-un ní orúkọ yẹn. Ìyá ti lọ sódò, bàbá ti lọ sóko. Mo ní kí Òkèjọbí pè mí lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tó bá di ọ̀la. Láti ojú fèrèsé ni mo ti ń rí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Ọ̀gọ̀njọ́ òru ni àwọn eléyi tún pariwo. Ta ni á kó àjọ ní oṣù tó ń bọ̀. Ó kígbe l’óhùn rara. Wàyíì, ó ye ká yànàná rẹ̀ wípé bí a ṣe ń lo èdè yàtọ̀ sí ara wọn. Túndé ti lọ gẹ’run ẹ̀. Májìyàgbé, tìẹ ò ní gbé n’ílé ọkọ. Aṣọ ìbora náà kò nípọn. Alóńgẹ rẹ́rin kàkàkà. Àwọn ajá igbó wà nínú igbó kìjikìji náà. Ọ̀rọ̀ ìfẹ́, bí àdánwò ni. Mo pàdé olùdarí ilé ìwé gíga mi ní ibi ìnáwó ní ìjẹẹ̀ta. Kí ló dé ti àga yí fi dọ̀tí tó báyi? Àya rẹ̀ já nígbà tó rí ẹkùn yẹn. Wọ́n ńi ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ló wọlé ní ìjọba ìbílẹ̀ Kájọlà. Mo fẹ́ lọ sí etí òkun láti lọ gbafẹ́. Abúlé wọn tóbi gan. Yẹtí mẹ́ta ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rà fuń-un. Ìgbéraga kò dára rárá. Màá máa wá wò yìn nílé láìpẹ́. Ojútikú wà ní ilé ìwé gíga ti Ìlú Èkó. Kò sí èrò ní’ta gbangba. Babátúńdé ti sọ owó nù si’lé tẹ́tẹ́. Ẹlẹ́dẹ̀ náà bí ọmọ mẹ́fà péré. Oò sì ní ṣ’aláì bímọ. Ìmọ́tótó ṣe pàtàkì fún àti dénà ààrùn. Kẹ́ẹ tún ilé ṣe kí a tó dé. Mo fẹ́ rán ọmọ méjì ní’ṣẹ́. Jìnádù pa ejò gígùn. Mo rí pẹ́pẹ́yẹ tí ọmọ mẹ́sàn-án wà lẹ́yìn rẹ̀. Mí ò ṣeré o; òdodo ọ̀rọ̀ ni. Omi tí mo fẹ́ mu wà nínu kòkò irin. Dáre ni akọ̀wé ẹgbẹ́ akọrin inú ìjọ wa. Bàba Wàídì mọ ẹni tó ni ilé epo yìí. Kíni m̀bá ti ṣe sọ pé mo gbọ́? Sa gbogbo ìpaà rẹ kí ọjọ́ ọ̀la rẹ́ lè suwọ̀n. Wọ́n ń ṣe orò ní Sáàgámù lọ́wọ́lọ́wọ́. Wọ́n gbàmí tọwọ́tẹsẹ̀ ní ilé ọkọ mi. Mo gbọ́ ìròyìn àwọn ọmọ ìyá méjì tí wọ́n fi ara wọn ṣe ògùn owó. Egúngún náà ni Yòrùbá máa ń pè ní ará ọ̀run. Ìlú ńlá ni Èkó. Ìṣoore-olúwa ni orúkọ tí wọ́n fún ilé náà. Wọ́n wà nílé ìgbọ̀nsẹ̀. Lọ mú ìró yẹn wá. Ta ló ni pángolo? A ti tọ́ka sí obì gbàǹja àti obì àbàtà. Mo fẹ́ràn aago yìí. A fẹ́ kí wọ́n ó dàgbà kí wọn ó dògbó. Ọṣẹ ni mo lọ rà. A ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ara wa. Kí á mà dan ìgbàgbọ́ wa wò. Òdòdó kan ni a wá já n’ílée yín. Kò sí oun tó ń bọ̀ lókè tí ilẹ̀ ò gbà. Àwọn ènìyàn súnmọ́ olódùmárè pẹ́kípẹ́kí. Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ náà ti yí dànù lórí iná. Ta ló fi j̣ẹ oyè Ajírọ́ba? Ọfà ba ọmọ ogun rè l’ẹ́sẹ̀. Kí ló ṣe ẹ́ ní’mú? Àwọn ọlọ́pàá ti gbá mi mú. Ti fèrèsé náà kì ẹfọn má baà wọlé. Àpò ìwé ẹ̀ wà nínú aṣọ mi. Ọmọ náà fẹ́ràn eré àgbéléwò bíi ẹlẹ́dàá ni. Ẹran méjì-méjì ló fi ṣe wá lálejò. Àrun jẹjẹrẹ ò dára. Aṣọ ńlá ni ọbá máa ń wọ̀ lọ sí jímọ̀. Mo máa dáàbò bò ẹ lọ́wọ́ gbogbo ìjọ̀gbọ̀n ayé. Ìbàjẹ́ ènìyàn kò dáṣẹ́ ọlọ́run dúró. Tí a bá ń sọ àṣìṣe ara wa, èyí kò ní jẹ́ kí okùn ìfẹ́ wa gùn. Lọ gbá ilẹ̀ àárín ilé àti ti ẹ̀yìnkùlé. Ṣé o ti gbée fún ọ̀gá ẹ? Owó ẹyọ là ń ná láyé àtijọ́. Láti mọ iṣẹ́ náà, ó gba ìfarabalẹ̀. Yàrá àwọn Similólúwa tóbi gan. Orí àdògán ni wọ́n ti ń ro’kà. Ẹ bá mi fi díẹ̀ sí oúnjẹ yíì. Wọ́n ti múná lọ. Èyí ni ọmọ tí mo sọ fún ẹ ní ìjẹẹ̀ta wípé ó ní ìka mẹ́fà. Àpadàsáburú ò ní jẹ́ ìpín wa o. Ìyá àwọn ọmọ tí ilé wọ́n wà ní ibùdókọ̀ kẹta sí ìhín ti bá àgbèrè lọ. Inú omi ni ẹja ń gbé. Àwẹ̀ìwẹ̀tán ni omi ọ̀sà. Ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tó farahàn nínú àwọn ìlànà yìí ni àrànmọ́. Mo fẹ́ ra àgbàdo. Ìwé ìròyìn márùn-ún n wọ́n kọ̀ọ́ sí. Àyà mí máa ń já nítorí a ò mọ bí ọ̀lá ṣe máa rí. Làpálàpá wà l’órí ẹ. Ìbejì ọ̀ràn ni wọ́n fẹ́ yà. Jẹ́ ki mo mọ̀ tí o bá ti ń lọ sí ilé yin. Gúsù orílẹ̀ èdè yìí ni mo ti wá. Máa tọ́jú mi, Jèhóvà ńlá. Mo ra bàtà mẹ́ta l’ọ́jà Akẹ̀sán. Bàbá àti ìyá mi ló fún mi lówó tí mo ná. Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni ó wù mí kí n ti ka ìwé fún Másítàsì mi. Abẹ́ igi ọdán ni wọ́n ti máa ń sábà pa ààló. Wá bá mi rẹ́ èékánnáà mi. Ṣòkòtò náà dára lára rẹ̀. Ẹ̀rín máa ń pa mí nígbà tí mo bá ń gbọ́ àwọn ìpolówó kànkan. Ìyàwó rẹ ní owó jùú lọ. Àwọn mìíràn gbàgbó pé bí èyàn ṣe ń d’àgbà si ló ṣe jẹ kó l’óye si. Tí óúnjẹ yẹ́n bá tutù, kò ní ṣe é jẹ mọ́. Bá mi gbé ìwé wá. Ó ti fẹ́rakù bí mo ṣe ń wòó yìí. Ó máa ń ṣe mí bíi kí a jọ máa wà ní gbogbo ìgbà. Àlùbọ́sà ni ó ń tà. Mo ti gun òkè Afárá rí. Mo nífẹ màmá mi. Wọ́n gbàgbọ́ pé iṣẹ́ tí àwọn fi orúkọ náà rán sí ọmọ bẹ́ẹ̀ yóò kó ipa ribiribi. Ilé-iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ni ìyàwóò mi kejì wà. Àwọn Ọmọ náà fẹ́ kọ́ èdè Yòrùbá. Ara ò ní ni wá o. Ọjọ́ burúkú èṣù gb’omi mu ni ọjọ́ náà jẹ́. Aṣá ló lọ gbé ọmọ adìyẹ lórí ibẹ̀. Ẹ̀yin ni atọ́kùn ètò náà, àbí? Mo túbá fún gbogbo àṣìṣe tí mo ti ṣe s’ẹ́yìn. Ìyàwó ẹlẹ́sẹ̀ osùn, rọra máa wolẹ̀. Gbólúwaga ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ibi tí ìyá rẹ rán-an ni. Oko obì lọ́tun, ti ọ̀gẹ̀dẹ̀ lósì. Ọlọ́fin ní orúkọ ẹni tí ó tẹ ìlú Ọ̀tà dó. Ó sọ pé ki n má bínú. Wọ́n na Àdùnní játijàti. O gbọdọ̀ gbọ́ ohun tí mo bá sọ fún ẹ, èmi ni mo bí ẹ. Atọ́batẹ́lẹ̀ ra ọ̀gẹ̀dẹ̀ wá. Adúrú ǹkan yìí ṣẹlẹ̀, oò dẹ̀ jẹ́ kí mo gbó? Ìyàtọ̀ gedegbe ló wà láàárín ikú àti ìyè. Àjàká lọ sí Ìlú Èkó. Ǹjẹ́ ìwọ́ tí dé Ìdúnmọ̀tà rí? Orí ẹní ni mo sùn mọ́jú. Àkàyìmọye ìwé ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Ajíbóyè Ọládìípò ti kọ́. Àárin gbùngbùn àríwá ni Atikú ti wá. Ṣé o mọ ìdí tí mo fi ṣe bẹ́ ẹ̀ bi? Lọ wo ẹ̀wà tí mò ń sè nínú kíṣìnì. Ó yà mí lẹ́nu, ètè mí ya pẹ̀lú. Ǹjẹ́ o ti gbọ́ oun tó ṣẹlẹ̀? Orí ibùsùn Àdìó ni Ṣẹfíù jókòó sí. Ní àná, ọkọ mi ò wá sílé. Jẹ́ kí n fún ẹ ní gbogbo ìfẹ́ mi pátápátá. Bísí jẹ́ ìyàwó kejì. Inú omi àti orí ilẹ̀ ni èyàn ti lè rí oònì. Ajé f’ilé wa ṣe ibùgbé ẹ̀. Ikúu M.K.O Abíọ́lá dun ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. Gángan ni ọ̀rọ̀ ilé ayé, bí ó ti kọjú sẹ́nìkan, ẹ̀yìn ló kọ sí ẹlòmíràn. Ààfin ni wọ́n ń pe Ìgà ní Ọ̀yọ́. Inú ń ro mí o. Bàbá yín ò ní pẹ́ dé o. Àwọ̣n ọmọ wọ̀nyí ti jáde lọ. Abẹ́ àtíbàbà ni ìpàdé náà yó ti wáyé. Bàbáa wa ló tún wá jọ́ba. Wùnmí fẹ́ràn kí ó máa jẹ eegun. Owó náà ká gbogbo ohun ta fẹ́ ṣe. Lọ wẹ̀ kí o yé rùn. Ìyá tó mọ ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi kó má ṣe mọ ìgbẹ̀yin ayé mi. Inuwọ̀ wà ní abẹ́ tábìlì. Kò mọ̀ ju kí ó ma kà’wé lọ. Ilé ò ní lé wa, ọ̀nà ò sì ní nà wá. Ó ń polówó ọjà. Fẹ́rànmi ti sá kúrò nílé iṣẹ́ ìjọba. Ìrètí nì orúkọ ọmọ àbúrò màmá mi. Tí mo bá gbàgbé ohun gbogbo, ojú rẹ ni mi ò le gbàgbé. Kí màmá tó lọ sọ́jà ló ti sọ fún mi kí n pàrọ̀ aṣọ àbúrò mi. Ọ̀rẹ́ pàtàkì ni èmi àti ẹ̀gbọ́n bàbá ẹ nígbà tó wà láyé. Kí ló ń s’áré jù nínú ìjàpá àti eku. Olódùmarè ní kí ẹ má sin òrìṣà kankan lẹ́yìn òun. Ifá ní pé, ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ ní kí wọ́n fi máa kóná àgbo fún àwọn tí ara wọn kò yá. Pa fẹ́rẹ́sẹ́ dé kí o bá mi ní ìsàlẹ̀. O jọ ẹni tí yóò ní ẹ̀mí gígùn. Èdùmàrè jọ̀wọ́ jẹ́ káyé ó yẹ wá. Ó ra ọtí fún wa, ẹ bá wa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Ayé laá jẹ, ka tó jọ̀run. Mi ò gbàgbọ́ pé Tinúadé lè pa ènìyàn. Ọ̀rọ̀ tó ṣ’àkàlàmàgò tó fi dẹ́kùn ẹ̀rín rínrín, bó ba ṣe gúnugún a wo kókò sórí ẹyìn ni. Bí Ọládùnúní àti Ọláfibọ̀ tilẹ̀ d’ẹ́se náà, wọn ti tọrọ àforíjì. Alágídí èyàn ni Odùújókòó. Ní àná, ò ń wò bí ẹyẹ t’ójò pa. Àwọn okùnrin ni ó pọ̀ njù nídìí iṣẹ́ orin dadakùádà. Ọ̀jọ̀gbọ́n ni ọmọ náà. Díẹ̀ ni tìẹ níbẹ̀, Abíkẹ́, ọmọ Monífádé, ará ìsokùn. Lọ gbé ẹní wá. Ọ̀dọ̀ Ṣẹ̀fíù ni mo ti yá ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà. Àwọn ọmọ náà mọ̀ pé ó dára láti wùwà rere. Ìrìn àjò ànà ò dẹrùn rárá, ẹnu gan kò lè ròyìn rẹ̀ tán. Akẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀. Ṣọ́’ra ṣe o, ayé gba jẹ́jẹ́. Olè náà sáré gba kọ̀rọ̀. Atẹ́ ti kúrò ní ile ìwée wa. Ajá dúdú ni ti wọn. Jẹ́ ká jọ jó. Mo rí nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀. Oṣù kẹwá ni Adéwùnmí yóò sẹ mọ̀-mí-n-mọ̀-ẹ́. Ẹyẹ agénifò tí ń fò Iójú ọ̀run, kílódé to ṣekú pa Akínsanmí? Bí ọkọ̀ náà ṣe bọ́ sinu kòtò ló mú kí ó forí gbá. Ìwé mẹ́rin ni ọ̀gbẹ́ni Caleb ní ka rà. Wón kun àtíkè sí ọrùn Àńjọlá. Ìdàgbàsókè tí ń bá ìlò ède Yorùbá nípa ìmọ̀-sáyẹ́ǹsì. Ìbálòpò tọkọtaya ni a ń sọ. Ọmọ ló kù ta ǹ tọ́rọ́ fún wọn. Orí páànù ni wón sá ẹran oníyọ̀ sí. T’akọ t’abo la dálé ayé. Ipele àkọ́kọ́ ní fásitì ni mo ti pàdé ìyàwó mi. Kò sí èyan rere kan lára ọmọ yẹn. Ilé-iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ kan ni Jákànde ni ó fi ọ̀rọ̀ náà lọ̀. Kò ní mú ọgbọ́n wá tí a ò bá dá owó tó kù padà. Ìjọ tí mo lọ lánàá wọ́n ń pariwo. Kò rí oorun sùn lálẹ́ àná; èyí múu bínú. Ọ̀rẹ́ kìí ṣe ẹnìkan tí ó kàn ń ṣe alábàápín ìgbà tí nnkan rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Mo gba ààyè ní ibi iṣé láti lè lọ fún ìrìn àjò náà. Ohun tí a ó fẹnu jóná lé lórí iṣẹ́ yìí ni èdè àwùjọ àwọn agbèrò àti awakọ̀. Àwọn ọdẹ etílé kìí wọ inú igbó kìjikìji. Ó lé tìróò s’ójú. Ó bá mi mú ẹran wá. Kò kúkú sírú ọlọ́run, Ọba tí kò ṣeé pè lẹ́jọ́. Etí rẹ̀ pẹ̀lú a sì máa gbọ́ ìgbọ́kùgbọ̀ọ́. Wọ́n fẹ́ràn láti máa jẹ àkàrà. Ìdíje ńlá gbáà ni àwọn ẹgbẹ ọdẹ ń fi Ìrèmọ̀jẹ́ Ògún ṣe. Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ẹ̀yà lítíréṣọ àbáláyé Yorùbá ni eré-oníṣe àbáláyé jẹ́. Olúwa yóò ṣọ́ ẹ di ọjọ́ ìkúnlẹ̀ o. Ó ti wa wèrè ni? Lọ ra ata’re wá. Aríìkẹ́ ni mo yàn láàyò jùlọ nínú gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi. Kí ló dé tí irọ́ rẹ pọ̀ tó báyìí? Òpó iná náà ti wó lulẹ̀. Àwọn tí wọ́n darí iná fún eré orí ìtàgé náà gbìyànjú. Jẹ́ kí á lọ bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun níbi tí enìkan ò ti mọ̀ wá. Akáloló ni Bídèmí nígbà tí ó ṣì kéré ṣùgbọ́n ó ti yàtọ̀ díẹ̀ ní sìnyí. Ìrìn-àjò èdá láyé Ọlọ́run ló mọ̀. Irun rẹ̀ ta kókó. Láti ojú fèrèsé mi, mo rí àwọn ọ̀dọ́ méjì̀ tí wọ́n ń tami oge. Edé mẹ́fà ni Músá fi mu gààrí. Ó ti jí ẹran jẹ nínú ìṣasùn. Ṣòkòtò funfun la wọ̀ lọ sí ilé ìjọ́sìn náà. Bí ìyá náà ṣe gbé ọmọ náà pọ̀n dára jọjọ. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ni wọ́n kọ́ mi bí wọ́n ṣe máa ń se oúnjẹ. Ayé ń lọ, à ń tọ̀ ọ́. Nínú gbogbo ìdáwọ́lé mi mo ríre. Ṣadé ṣiṣẹ́ ìwádi lọ sí ilẹ̀ Àríwá. Kí ni wọ́n ń polówó. Àṣé ayé kọ́ la wà nílẹ̀ wa rárá, mo kí ajé kúùkàlẹ̀. Ìwé mélòó lo ti kà. Nínú ère àgbéléwọ̀ náà la ti rí ibi tí ọkọ ti fọ’nu fún aya. Ẹ̀gbọ́n mi ti ṣe ìbéyàwó ní ọ̀sẹ̀ tó lọ. Irú ìbéèrè wo lèyí? Wọn fi ẹ̀mí ìmoore hàn. Gbogbo ara ni mo fi ń kí ẹ. Tóbi ní òun ò fẹ́ rí ẹnikẹ́ni lénìí. Oríṣiríṣi ọgbọ́n ni àwọn bàbá wa máa ń ta láti de ọmọ tí ó bá jẹ́ àbíkú mọ́lẹ̀. Wọ́n ti lọ ṣán ara wọn lẹ́yìn lẹ́yìn wàhálà púpọ̀. Wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fun ọmọ yẹn ní inú. Tí mo bá lè ṣe’pò kíní nínú ìdíje yìíì, bàbá mi á ra ẹ̀bún fún mi, èyì dá mi lójú. Oṣhòdì ni ilé iṣẹ́ Alfa wà. Ní ‘jọ́ tí Herbert rí Monisọ́lá, kò lè gbójú kúrò lára rẹ̀; Ó fẹ́ẹ̀ lè ma játọ́ lẹ́nu. Àná ò le jẹ́ t’òní, tòní ò sì jọ t’ọ̀la. Mo fẹ́ràn ìsọkúsọ lọ́jọ́ Sátidé. Mo fẹ́ kọ́ bí wọ́n ti ń tẹ dùùrù. Ẹ̀yọ̀, Gẹ̀lẹ̀dẹ́ àti Eégún ni àwọn ọdún ìbílẹ̀ tí mo fẹ́ràn jù. Ìyá wọn ti dolóògbé. Nínú bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá ni wọ́n ti jáwé olúborí. Ọmọ́yẹlẹ́ ti yọ fáìlì náà kúrò ní ibi tí a kóo sí. Onímọ̀ ìṣègùn ni ọmọ mí sọ pé òun fẹ́ fẹ́. Ọjọ́ ọla mi ló jẹmí lógún. Eṣinṣín wá tìlẹ̀kùn ṣáláńgá mọ́rí, ó l’óun ò ní jáde àf’ìgbà tí wọ́n bá fún-un n’íyàwó. Ki lo kùn sí ètè? Èrí mìíràn tí ó fi ìdí ìgbàgbọ́ Yorùbá hàn nípa Àbíkú wà nínú ẹṣẹ̀ ifá. Ọkọ̀ akérò ni mo wọ̀. Aríṣekọ́lá ṣe dáadáa nínú ìdánwò. Ẹlẹ́nu róbótó bí orí ìgò. A gbàgbọ́ pé wọ́n jẹ́ ẹ̀mí àwọn ará ọ̀run tí wọ́n máa ń bẹ ilé-ayé wò. Ó darí ìpàdé náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Bàtà mi dà? Níbo lo kó wọn sí? Wọ́n ti mú Èmánúẹ̀lì lọ sí ibi tí yóò ti kọ́ bí wọ́n ti ń ṣe bàtà. Òṣùwọ̀n mẹ́jọmẹ́jọ lóri omi. Kádírí ń jẹun bíi wọ̀bìà. Pẹ́pẹ́yẹ máa ń wè nínú omi bẹ́ẹ̀ wọ́n ń rìn lórí ilẹ̀. Ẹfọ̀n mẹ́ta la gbọ́ pé ọdẹ náà pa. Omí ti dànù. Ṣé oṣó ni ẹ́ ni tàbí iwin? Kí ló dé tí o sá aṣọ tútù sí inú ilé. Ìyá ọkọọ̀ rẹ ló ń pè ọ́. Ilé-iṣẹ́ ti bàbá Bọ̀dé tí ń ṣiṣẹ́ ló ṣe agbátẹrù ìdíje náà. Àwámárììdí ni Ifá. Aláriwo ọmọ ni ẹ́. Ta ẹ̀pà fún mi kí ebi má pa mí kú. A ṣì ní ọ̀pọ̀ ǹkan láti mọ̀ nípa àwọn àdán àti iye ẹ̀ya tó wà. Wọ́n pa ọmọ yín lẹ́kún. Ètò ẹ̀kọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ ṣe pàtàkì. Mary Slessor ló dá’wọ́ kí a máa pa ìbejì dúró ní orílẹ̀-èdè Nìgéríà. Olùyàwòrán ni Olúwatóbilọ́ba. Àdúrà fún àwọn ológun Orílẹ̀-Èdè wa àti ìdílé wọn. Ọ̀gá ni Bísóyè níbi ká máa ṣe ìwádìí nípa ìmọ̀ èrò. Àpá kan wà lẹ́yìn ọrùn mi. Àgbàrá ti wọ́ oko bàbá àgbà lọ. Pàtàkì ni àdúrà nínú ohunkóhun. Ẹ̀yìn ilẹ̀kùn ni a máa ń kó ìgbálẹ̀ àti ìkólẹ̀ sí. Ìjọba ti ní kí wọ́n tilé náà pa nítori wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́. Orí ibùsùn yìí ni gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀. Orúkọ ìwé náà ni Mátìíkú. Òǹkà Yorùbá ni mo kọ́ àwọn ènìyàn níbi ìpàdé àná. Èmi ni mo bá àbúrò mi ṣe iṣẹ́ àmúrelé rẹ̀. Ẹnu-Ọwá la ti ń d’ádé. Òòrùn yìí mú gan-an o. Ibo lo ti lọ fọ’bọ́? Mo kórira irọ́ láyé mi. Mo fẹ́ran àgbàdo sísè. Ọlọ́mọ jogún ayé; Erín jogún ọ̀la. Àńjọláolúwa lorúkọ àmútọ̀runwá rẹ̀. Èdè ni à ń lò ní àwùjọ èèyàn púpọ̀, kí àgbọye àti àsọyé lè wà. Níbi tí mo rìnriǹ àjò lọ, ará oko gbáà ni wọ́n. Wọn-òn dá ohun kan mọ̀. Ikú á poníṣègùn bí ẹni tí o m’egbò. Ìgbà wo ni wọ́n ma tó ṣe ọdún ẹ̀yọ̀. Bóyá màá lọ ra mọ́in-mọ́in àt’ẹ̀kọ. Ọpọlọ ọmọ yẹn dà bíi ti Dámilọ́lá. Ọmọ ọba kìí sùn ìta. Ọ̀kan ni ènìyàn ó f’ọwọ́ mú. Imú ọmọ ìkókó náà dọ̀tí. Olorì ní kí a pe àwọn ẹ̀sọ́ wá. Ọ̀dájú n'ikú, bó ṣe ń pa lọ́tùn-ún ló ń pa lósì. Ọmọbìnrin kán wà, ó bímọ méjì, orúkọ àwọn ọmọ náà ni Ọmọ́ṣewà àti Adétutù. Àbùbùtán bíi omi òkun. Ṣé o ti rí ẹran ajá rí. Tí ẹ bá wọ inu ilé wa, àwòrán kan wà lẹ́gbe ibùsùn; Ẹ bá mi múu wá. A ti gé igi kan lulẹ̀. Ọmọ màmá ẹ̀ ni Túndé. Mo máa wà ní agbègbè Tinúbú ní agogo mẹ́wa ọ̀la. Ọdúnm̀bákú ni wọn pe ọdún náà, nítorí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀. Èèyàn mélo lo fẹ́ rí? Mo ò tíì wẹ láti àárọ̀. Ìwọ náà ti délẹ̀ yí, omí ti ta síi díẹ̀. Ọ̀dẹ̀ burúkú l’ọmọ Ajíbóyè yìí tó dá mi dúró. Fọlámí Ọlájídé lorúkọ ọ̀rẹ́ mi àtàtà. Gbogbo wa ni ọ̀rọ̀ yìí kàn. Jàlabíà dúdú ni mo wọ̀ lọ kí ìrun yídì ní ọjọ́ ọdún. Ikú á sọ gbogbo ilé d’ahoro. Òkè pọ̀ ní Ìṣẹ̀yìn ju Ọ̀yọ́ lọ. Ilé ìjọ ni a ti ṣe ọjọ́ ìbí ọ̀rẹ́ mi. Nígbà tí ogún wọ ìlú, abẹ́ àpáta ni èmi àti àwọn mòlẹ́bí mi fara ṣọkọ sí. Nínú èrò tí Elédùmarè fi jíǹkí ẹ̀yà Yòrùbá ni ọ̀nà tí a fi ń ṣe òǹkà tó múná dóko. Mọ́ṣáláṣí wà ní ara ilé òhún. Ata ni Bọ́láfadé ń tà láti rán ara rẹ̀ lọ sí ilé-ìwé. Àwọn ọmọ tí kò bá ti f’etí sílẹ̀, ẹgba ni irú wọn máa ń jẹ. Àwon ìyàwó ilé náà ṣàbòsí ìyálé wọn. Ọmọ Ọba ni Adédọlápọ̀. Ẹ yan aṣojú láàárín yìn. Bùgan tí bàbá mú wálé dùn púpọ̀. Fálànà jẹ́ ògbóǹtarìgì agbẹjẹ́rò àgbà ní orílẹ̀ èdè yìí. Àwọn mẹ́sàn-an ni wọ́n jọ ń dá àjọ náà. Gbàjarè! Wọ́n ń wá ọmọ'bìrin kékeré kan o. Ilà gọ̀m̀bọ̀ ni Tìmílẹ́yìn kọ. Wọ́n wáa níyẹ̀wù àgbà. Màlú mẹ́ta la pa fún ọdún. Ẹ̀gbín ni ká má bọ̀wọ̀ f’’ọ́ba. Ọlọ́run má jẹ a ṣòfò èmí. Ìfẹ́ tí a fẹ́ adìyẹ ò dẹ́nu. Fi sí àarín ọkọ̀ yẹn. Kí la lè jẹ lówurọ̀ yìí, ebi gan ni mo bá jí. Nínú̀ ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá tí wọ́n dá fún Tájù, ọdún mẹ́wàá ló lò níbẹ̀. Àkàndùn ló mú Ìyániẃurà lọ́wọ́. Ìyàwó Adéfarasín bàá nínú jẹ́. Ọ̀lẹ ni ọmọ yẹn, bí mo ṣe gbọ́. Àwọn mélòó ló wà nínú yàrá yìíi? Orin àti ìlù ṣe pàtàkì níbi eré ìdánilárayá. Pè mí l’órúkọ mi, Ṣaléwá. Orí ló ń sin ni tá fi ń kọ́lémọ́lé. Ọ̀dẹ̀ ò wù mí lọ. Kí Ọlọ́run ṣe ohun gbogbo ní dédé. A fẹ́ lọ dá aṣọ náà padà sí ilé aránṣọ. Akíntọ́pẹ́ jẹ́ àna sí Ògúnlésì. Orí ọ̀pẹ ni a ti máa ń rí ẹmu. Ó ti padà dé láti òkè òkun. Jákọ́bù ń sáré yípo ọgbà náà. Ọ̀mùtí paraku ni Ọláṣayọ̀. Ó ti rẹ̀ wá púpọ̀. Lọ ra ẹ̀pà àti gúgúrú wá. Wọ́n ni ilé àwọn Jẹ̀lílì l’àwọn ń lò. Aṣọ àdìrẹ pọ̀ ní ìlú Abẹ́òkúta. Ọjà ńlá ni Àkẹ̀sán jẹ́. Mi ò n’ífẹ sí àpèjọ àbòsí. Ẹ wo bó ṣe da ẹnú sílẹ̀. Mo ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà márun pẹ̀lú díẹ̀. Ẹ̀sìn òkèrè ni ẹ̀sin Krìstẹ́nì. Ẹnikẹ́ni tí ìwọ́ bá nípá láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún òun ni ẹnìkejì re. Ṣ’ara gírí kí o lo àwọn ògùn tí Dókítà kọ fún ẹ. Ẹ̀rín pa mí gidi nígbà tí mo gbọ́. Ní ọjọ́ kan, ó múra oko ọdẹ, pẹ̀lú ìhámọ́ra. Mo ṣèṣẹ̀ dé láti Kalifóníà ni. Fi ara balẹ̀ ṣá, má ṣè’jọ̀gbọ̀n. Wọn ó tíì jáde ní ilé ìwé àwọn Démiládé. Tọkọtaya ara ilẹ̀kùn náà ti bàjẹ́. Ayélàágbé ò fẹ́ràn kí ó máa rí àwọn àlejò ní ilé rẹ̀. A ṣèbà fún Ọba tó layé tó lọ̀run. Wọ́n ti ti ilé ìtajà yín pa. Òkuta tó bá lórí lo mú kí ẹyín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fò yọ lẹ́nu rẹ̀. Iṣẹ́ aránṣọ ni isẹ́ tí Lọlá ń kọ́. Ó dára kí ìyàwó máa ṣisẹ́. Ibo ni Sànúsí wà? A ti mú Doyin lọ sẹ́nu ìkọ́ṣẹ́. Mo ò ní já ẹ ku’lẹ̀. Ibí lo sùn mòjú. Ibo lẹ fi ọ̀bẹ sí? Ìtan fèyíkọ́gbọ́n ni eléyìí fún gbogbo ẹ̀dá Ádámọ̀. Olórí ilé ló lágbára àti dáríji ẹni tó bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí. Mo tọrọ àforíjì pé mi ò lè dé ibi tí wọ́n wà lónìí. Ìyàwó ilé tí ò mọ oúnjẹ sè, kí ni ká ti gbọ́? Abọ̀rìṣà ni yín tẹ́lẹ̀. Ojúmọ́ ire, ojúmọ́ ayọ̀. Ẹ ò ká aṣọ wọ’lé kí òjò tó bẹ̀rẹ̀. Ṣòkòtò olómi aró ló wọ̀ lána. Ó fẹ́rẹ̀ má sí ìlú ilẹ̀ Yorùbá kan tí wọn kìí tií ṣe ọdún ìbílẹ̀ níbẹ̀ mọ́. Ẹdun náà ni wọ́n pè ní ọ̀bọ. Motúnráyọ̀ ló jáwé olúborí. Ògì ni màma Pamílẹ́rin ń tà. Koríko pọ̀ ní agbègbè náà. Ìjíròrò yó ti máa lọ lábẹ́lẹ̀ lori ètò ìdìbò tí ń bọ̀ lọ́nà. Nígbà tí ó di òru, Ìjàpá múra, ó gbé agbọ̀n kan rù. Ohùn ọmọ náà dùn. Àwọn ohun èlò akọrin ni ìlù, fèrè, jìtá, àti agogo. Igi gogoro ni wọ́n gé. Ẹ̀sìn ilẹ̀ wa ni ẹ̀sìn Àbáláyé. Ẹ̀yà Ìgbò ni ẹni tí Mọ̀rúfù fẹ́. Obì jẹ́ ohun ìpanu àwọn àgbàlagbà. Ọlọ́run nìkan ló mọ ohun tó ń ṣe fún àwọn ará ìlú. Ijó, ẹ̀rín, ayọ̀, àti ọpẹ́ ló yẹ wá. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kò káàárẹ̀ láti máa wá sí ìpàdé. Àwọn ọmọ ogun orí omi wà níbẹ̀. Olówó ló layé ni wọ́n máa ń wí. Kú iṣẹ́ takuntakun, ìwọ ọmọ yìíì. Fúnmi dé ìgò s’ójú. Ìlù àti agogo máa ń sábà jẹyọ nínu orin. Àwọn ọmọ kékeké ti pọ̀ jú ní àdúgbò yẹn. Mo fi ẹnu kòó l’ẹnu. Ó fẹ́ pẹ́ láyé ju bí ó ti yẹ lọ. Kí ni ìdí tí àwọn èyàn mìíràn fi máa ń jẹ́ àfín? Àlùfáà ń wàásù fú àwọn ọmọ ìjọ. Àti ọjọ́ pípẹ́ làwọn baba wọ́n ti ń rejú ogun. Fásitì Èkó ni ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Àrẹ̀mú gbà pé ó dára jù ní orílè èdè yìí. Orí ń yún mi láti ìjẹta. Àsáwọ̀ wà nínú oúnjẹ náà. Bàbá kan wà tó sọ fún egúngún pé kí ó jíṣẹ́ fún ọmọ òun pé kó fi àgùtàn rúbọ. Àmínátù ní òun fẹ́ jẹ́ kí mo fẹ́ òun gẹ́gẹ́ bíi ìyàwó. Àkàndé ti kiri ọjà lọ. Àkọtọ́ òde òní yàtọ̀ sí ti àtijọ́. Ẹ kú àṣekù ọdún. Ó nífẹ láti máa mú ajá rẹ̀ kiri. Ení bí ení lọ́mọdé ń kawó. Ó ṣì jẹ ẹgbẹ́ ní àpo kan. Òjó ti ṣú láti ìdájí, kò dẹ̀ tíì rọ̀. Ìfẹ́ mi si ẹ kì í ṣe tẹ̀tàn rárá. Awakọ̀ náà ti dí òpópónà. Kòsọ́kọ́ ni àbígbẹ̀yìn bàbá tirẹ̀. Ṣé ó ń dùn mọ́ ẹ? Ìgbà yí ni ọ̀la mi tó kún. Mo júbà àwọn tó layé, àwọn tọ́ ti wà k’áwa tó d'áyé. Mi ò tíì mọ oun tí mo máa jẹ lónìí. Gàní ti lọ sí Ìlúu Mẹ́kà. Owó ni kókó o. Àmọ̀jù ní ń b’ẹkùn sàárè jẹ́. A máa lọ gba ilé sí Àkóbọ̀. Kí ló dé tí o jí Bídèmí sílè. Ifo ló mú Yéwandé lójú. Tó bá yá ẹẹ́ máa bú'jọba, ṣóun tó ṣe ó bójú mu? Màmá ni ki a máa fọ ẹsẹ̀ kí a tó bọ́ sórí ibùsùn. Ó ti fi orí gbé òwú aláǹtakùn. Wọ́n mú ọmọ náà ṣeré. Àt’àná ni mo ti ń sùn. Inú igbó ni ẹfọ̀n máa ń wà. Bàbángídá ti ra mọ́tò kó tó lọ sí Hajj. Mo máa dúró dè ẹ́ ní ẹ̀bá ọ̀nà. Kátikàti bíi ọbẹ̀ onírẹsì ni gbogbo àwọn ọmọge ìṣẹ̀yín ń ṣe. Ọ̀làjú àti ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá ti ń mú kí àwọn àṣà àti ìṣe wá dẹnukọlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ la rí àwọn mìíràn tí ara wọ́n balẹ̀. Owó tó san ti pé. Ẹ̀yin àtùpà náà ti fọ́. Má jẹ́ kó dùn mí. Èyí tí ó wá tún ṣe pàtàkì jùlọ ni wípé àwọn eniyan gbàgbọ́ pe ẹ̀mí ń bẹ lẹ́yìn ikú. Kò fẹ́ kí á ṣeré ìfẹ́. Kí ló dé tí o ní ìkàánú fún mi tó bẹ́ẹ̀? A ti parí ìjà wa lánàá. Ó dà bí ẹni pé dàda ni ọmọ náà fẹ́ jẹ́. Arẹwà ni ọmọbìrin náà ní gbogbo ìgbà tí mo ríi. Ìwọ-oòrùn Gúsù orílẹ̀-èdè Faransé. Akókóró ló múu l’ẹ́yìn. Ọ̀nà ibo ni Admiralty wà? Ẹ̀gbọ́n mi ti ṣe ìkómọ ní ọ̀sẹ̀ tó lọ. Mo nílò èsì ìdánwò gidi fún ìtẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ mi. Ọ̀gá ni Bísólì Ẹlẹ́shin lọ́jọ́kọ́. Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ èdá èdè lìgúísììkì ni mo jẹ́. Kílàsì àkọ́kọ́ ni a ti kọ́ nípa Fònọ̀lọjí. Mo gbádùn yàrá tí mo wà. Tutù ní èjí ní eyín rẹ̀. Ẹ fún ọmọ l’ọ́mú fún oṣù mẹ́sàn-án. Bí a ṣe ń gbà ó nínú wàhálà kan lo ń bọ́ sí òmíràn. Mo fẹ́ jẹ̀’ka. Ilé ìtura tí a dé sí tóbi jọ̀jọ̀, ìlú Ọ̀yọ́ ló wà. Ilé ta fi ìtọ́ mọ, ìrì ni yóò wọ̀ọ́. Ọkọ ìya Bádé ti ṣaláìsí. Akitiyan àwọn ajíhìnrere tí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ àkotọ́ èdè Yorùbá kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Òjo pa wá dé ìbàdàn ni níjọ́ náà. A ti tọ́ka sí igi obì gẹ́gẹ́ bí igi owó pàtàkì kan láwùjọ Yorùbá. Àtakọ àtabo, èwo ni kì í ṣ’ọmọ. Kí ló dé tí wọ́n ṣẹ́ oyún fún-un? Olámìdé ti gbé àtẹ wàhálà rẹ̀ dé. A kọ́kọ́ júbà ki a tó lọ òde eré. Èkée Shíttù ti pọ̀ jù. Ọmọ náà ní ìgbéraga púpọ̀. Mo ti pinu láti má bèèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọwọ́ enìkankan. Ọba nìkan ló lè jó sí ìlu gbẹ̀du. Tó bá di ọdún tó ń bọ̀, mo fẹ́ lọ ṣe ọdún Kérésì ní ìlú mi. Ejò paramọ́lẹ̀ burú púpọ̀. Mo fẹ́ ra ẹyin bíbọ̀. Agbejọ́rò náà kú l’ówurọ̀ yìí. Orúkọ ṣe pàtàkì, ó ṣe kókó; kò sí nǹkan tí a dá tí kò ní orúkọ. Tí mo bá rí aláboyún, àyà mí ma ń là gàràgà. Awólọ́wọ̀ ṣe díẹ̀ nínú ètò òṣèlù orílẹ̀ èdè yìí. Alájẹṣu ọmọ ni Táíwò. Ẹ má lọ sínúu'gbó lóru o. Wákàtí kan ni mo fún ẹ láti dé ibí. Ṣé o wà ní orí Twitter? Ejò náà gbé ẹran mì. Àwọn alápatà jẹ́ àwọn ènìyàn tó máa ń pa ẹran fún títà. Orísirísi ìtàn ìwásẹ̀ ni ó sọ nípa àwọn orísun wa, láti òkè dé’lẹ̀. Ìmọ̀ràn náà dára, a ó múu lò. Jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ fún waà. Wọ́n lọ ra ìrèké. Nígbà tí mo dé ilé wọn, bàbá wọn ni mo kọ́kọ́ rí. Mo ò lè wá kú nítorí iṣẹ́ ẹni ẹlẹ́ni. Mo sọ fún Ajírébi pé tí ó bá ti ráyè kí ó wá kí mi nílé. Òòrùn ò tíì wọ̀ tán. Bàbá mi ní ọ̀rọ̀ kán wà tí òun fẹ́ bá mi sọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ni wọ́n ma ń bá ìyá wọn rẹ́ ṣùgbọ́n báyi kọ́ lọ̀rọ̀ rí fún Jayé. Fájídé ò ní ọpọlọ bó tilẹ̀ wù kó kéré mọ. Wọ́n ta ọfà fun jagunjagun náà láyà. Ó ní ìmọ̀ púpọ́ ní ọpọlọ. Ìdí tí mo fi fẹ́ràn ayé oko ni pé gbogbo nǹkan ló wà létòlé. Màmá mi, mo ti yó. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ni mo rí kọ níbi ìpàdé yẹn. Ajá máa ń jẹ ìgbẹ́ lójú ọ̀nà. Gbogbo òbí ló ń gbàdúrà ọmọ tó máa sanjọ́. Ìgbà tí ó ti ilẹ̀ mímọ́ dé ni ó ṣe sàráà. Mo dúpẹ́ ore àtìgbàdégbà olúwa. Dadakùádà jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀na ìgbé àṣà àti ìṣẹ́ ilẹ̀ Yorùbá lárugẹ. Àkàrà àti Ògì òyìnbó ni ìyàwó mi sè l’ówurọ̀ àná. Oríṣiríṣi ẹja ló wà níbẹ̀. Mo ti gbọ́ ìmọ̀ràn ẹ. Àmàlà ni Simí jẹ fún oúnjẹ ọ̀sán. Ọ̀gbẹ́ni, fi mí sílẹ̀ jọ̀ọ́. Inú kòtò ni mọ́tò náà já sí. Ọ̀mọ̀wé Ọládèjì wà nínú ọ́fìsì rẹ̀. Ológbò náà ń lé eku kiri nínú ilé. Àwọn wèrè l’àwọn olóṣèlúu wa o. Fúnmi ti sọ̀rọ̀ nípa òkè kan fún mi rí níbi ìpàdé kan ní Ìkòyí. Ó fún-un lọ́tí mu. Ẹ má jẹ kí n fẹ̀fun. Ìgbàgbọ́ mi dúró lórí olúwa. Ẹgbẹ̀rún ahọ́n kò tó láti yìn ọ́. Asọ̀rọ̀ sọ bótó ni Kòfowórọlá. Mú ṣíbí yẹn kúrò nílẹ̀. Moyọ̀ àti Bíbí ń bínú sí ara wọn. Ó dàbí ẹni pé àgùntàn Bísí sanra ju ti Bọ́lá lọ. Ikún wà ní imú rẹ. Ẹ̀rọ ayélujára máa ń parọ́ nígbà míràn. Moróunkẹ́ fọ́ ọkàn mi sí wẹ́wẹ́. Mo ra ìwé mẹ́ta níbẹ̀. Ní ìgbà láíláí, ọ̀rẹ́ ni ìjàpá àti àdàbà jẹ́ sí ara wọn. Àwọn ọjà yìí ò tutù. Tí mo bá ní mi ò rin ìrìn àjò báyi rí, irọ́ ni mo pa. Ta ló gbé ọmọ jù sórí àkìtàn? Ikú á pa babaláwo bí ẹnI tí ò gbọ́fá rí. Iná gbé Adétiba nígbà tó fọwọ́ kan òpó iná. Lọ fá irun rẹ kó tó wù. Táyé mọ ìwé ju kẹ́hìndé lọ. A dúpẹ́, Ṣé wọ́n ń bẹ lálàáfíà ara? Bíbíire, Tìmílẹ́yìn àti Ṣẹ́gun jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Púpọ̀ nínú àwọn ọmọ Nàìjíríà ni wọ́n máa ń jẹ ìrẹsì. Ìlú wa ni wọn yó ti ṣe àṣekágbá òkú màmá àgbà kékeré. Gbọ̀gàn àṣà ìbílẹ̀ ni ijó náà ti wáyé. Bá mi bu omi mímu wá nínu ìkòkò tó wà l'ábàáwọlé. Fún mi ní aṣọ yìí, mo ní’fẹ rẹ̀. Ohun tí ó dára ni láti wà pẹ̀lú enìkan tì èèyàn fẹ́ràn. Lọ fọn ikun’mú rẹ dànù. Ẹ gba Jésù s’ayé yín. Ó yẹ kí n yọjú síi yín láìpẹ́. Wẹ̀mímọ́ rò pé òún gbọ́n. Kan ìlẹ̀kùn pẹ̀lú sùúrù. Baba ńlá ìyà ni won ìbá jẹ tí m bá rí wọn mú. Ìgbà tí Olùwa rẹ̀ dé ni Fadérẹra dákẹ́. Hoògùn abẹnu gọ̀ǹgọ̀ ni wọ́n ń pèé. Mo fẹ́ràn irun orí rẹ̀. Orin náà ń fa ọkàn mi. Ó bí ìkẹta, bákan náà tún ni. Mò ń lọ sí ọjà àwọn eléwé ọmọ. Èdè mẹ́ta ni mo gbọ́ láti kékeré. Wàhálà l’ọ́tùún, rògbòdìyàn l’ósì. Ta ló fi ọṣẹ síbí? Ó ti dùbúlẹ̀ sórí ìbùsùn. Bọ̀dá Ràṣídì ni wọ́n fún Òkìkí ní owó oúnjẹ àárò yìí. Oyún náà ti pé oṣù mẹ́jo, Ìyá Bọ́lá oò ní pẹ́ já ẹrù náà kalẹ̀. Bíléèdì gé ọmọ náà ní’ka. Ilẹ̀kùn yàrá Tádé ti bàjẹ́. Jẹ́ ka jọ lọ jẹun níta. Irú àṣìtẹ̀ burúkú wo ni èyí? Àṣá gbé ọmọ adìẹ fò lọ. Abíọ́nà ní òun lọ rí Adé ní ago mẹ́wa òní. Ẹniyàn mẹ́rin ló ti ra ọkọ̀ tuntun láti ọdún tó kọjá. Nínú gbogbo ilé ìwòsàn agbègbè yí, ti ọ̀nà òpópónà òkìtìpupa ni ó dára díẹ̀. Ọmọ náà kò m’ará mú, àfi bíi ará oko. Ọ̀gá ni Sàmù nínú ká ya àwòrán aláràmbar. Ọpọlọ yín ni mo fẹ́ yá lò. Orúkọ Yòrùbá jẹ́ àkàìmọye. Ọ̀rẹ́ mi tuntun tí mo ṣẹ̀ pàdé ní patí kan ni. Ikú kò go’owó, kò gb’ẹ̀bẹ̀. Ọlárótìwọ́n sùn fọnfọn bí ẹ̀fọ̣n. Kọ́lápọ̀ jábọ́ sínu gọ́tà. Ẹni tó bá ń jini láya kò lè fojú ire wo’ni. Ọmọ ẹlẹ́pà ti ń sá lọ. Ọmọ bàba olówó ni mí. Kọ́bọ́ọ̀dù rẹ̀ ti bàjẹ́. Oyíndà ti sọnù lọ́nà. Ó ń bọ̀ wá, àwọn làá dẹẹ́ dèé. Ìkọta ni ilé tí Similólúwa ń gbé wà. Oúnjẹ kékeré ló sè lọ fún-un. Ẹsítẹ́tì náà rẹwà púpọ̀. Gbogbo àwọn ìṣòwò pátápátá jẹ́ ti ìjọba. Ní ọjọ́ ìbí Adérónkẹ́, pẹ́pẹ́yẹ p’ọmọ, a f’ilé pọtí, a f’ònà rokà. Ọlámide a máa fi gbogbo ọ̀rọ̀ ṣàwàdà, àwàdà sì máa ń kóbáa nígbà mìíràn. Ilé-ifẹ̀ ni ọdún Ifá ti máa ń bẹ̀rẹ̀ káàkiri gbogbo àgbáńlá ayé. Ikú Olóògbé Dúró Ládiípọ̀ dun gbogbo ìlú. Ọlórun má jẹ ka wáyé òfìfo. Ìbọn jẹ́ irinṣẹ́ pàtàkì fún àwọn ọde. Mo rí àwọn alábójútó ilé ìwòsàn kan tí ó ń mú kí ohun tí a gbà sílẹ̀ dára. Jẹ́ kí ó ṣe bí ó bá ṣe fẹ́. Tiwátọ́pẹ́ fẹ́ Tiwaladé. Ó yẹ kí a gbádùn ayé ni. Ṣé gbogbo ìgbà ni òtútù máa ń mú ìwọ ni? Gbogbo àwọn ọ̀dọ́ ló fẹ́ sá kúrò l’órílẹ̀-èdè yíì. Kí ló dé tí ò ń tẹ̀ mí lọ́rùn? Bàbá Ọba ni wọ́n ń pè wọ́n. Iṣẹ́ tó dára ni iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀dá èdè. Wàhálà ti mo fi ara ṣé pò lénìí. Nígbà kan rí, ó ní’fẹ̀ẹ́ẹ Bọ́lá. Mo rí àrà meèrírí, ó kọjá ohun tí mo ti gbọ́ tẹ́lẹ̀. Iná ìjọba máa ń wà dada ní agbègbè Ilémobọ́lá. Orí mi ni kẹ́ẹ wò. Ọ̀gágun Abéégúnrín àti àwọn ọmọ ogun àpapọ̀ ti lọ sójú ogun. Mọ́ṣáláṣí ni mo ti lọ gba kọ́kọ́rọ́ lọ́wọ Bọ̀dé. Báwo ni ọmọ ogójì ọdún ṣe máa fẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún? Èyí ni ó mú wa fi òwe wá àwọn oun tó sọnù sínú ọ̀rọ̀ Yorùbá. Ẹni yára lòòṣà òkè ń bá dá sí tirẹ̀. Mo máa lọ sí Àbújá ní oṣù kẹ̀sàán. Àwọn bàba bàbá mi ló tẹ ìlé yìí dò. Kí ni ìdí pàtàkì tó fi yẹ kí a kọ́ ilé yìí? Ibi tí mo fẹ́ yà ṣì pọ̀ gan. Padà wá ní ọ̀la jàre. Ta ló jẹ gbogbo oúnjẹ inú abọ́ tán? Ilé títúnṣe àti ọmọ títọ́ ni iṣẹ́ ti àwọn ìyá nígbà yẹn. Dáfídì ní ọmọ bàba olówó ni òún jẹ́. Lára àwọn ohun tí a fi máa ń dáná nílé ni ìkòkò àti àdògán. Ibà ló ń ṣe é látàárọ̀. Ǹjẹ́ wọ́n ti kọ ilà fún ọmọ náà bí? Kòkòrò gé Baṣọ̀run jẹ. Bá mi gbá ilẹ̀ sí Bariga. Ìwọ̀ǹba l'omidan ń sunwọ̀n mọ. Ọkọ̀ náà ti bàjẹ́. Ra ọtí tàbí ẹmu fún wa. Ọmọ tí a bí tí ó ń súnkún tọ̀san tòru. Ilé ìgbọ̀nsẹ̀ náà rẹwà. Ẹ jẹ́ kí a na sùúrù sí gbogbo wàhálà tó ń tàn kálẹ̀ yí. Ìfọkànbalẹ̀ máa ń wà ní ọ̀pọ̀ ìgbà tí ènìyàn bá lówó lọ́wọ́. Ta ló fi omi tí mo pọn wẹ̀. Ọọ̀ purọ́, bẹ́ẹ̀ gan lọ̀rọ̀ rí. Ìyá Fátùrótì ni ó ń ṣe ìnáwó lọ́jọ́ yẹn. Àwọn ọmọ ogun orí ilẹ̀ ń bọ̀. Mo ti gba Jésù sáyé mi. Lára ohun èlò aṣọ híhún ni òfì àti òwú. Ó yẹ kí ó sọ fún mi ná kó tó di pé ó gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá àgbà. A ti sanwó tí wọ́n ní ká san. Ó ń gbìyànjú láti tú mi jẹ. Àwọn adánilárayá náà mọ̀ọ́ jó púpọ̀. Kò s’ẹ́ni tó mọ Ifá tán. Mi ò kí n fi bẹ́ẹ̀ ṣeré níta. Òṣogbo ni wọ́n ti gbé àgbò náà bọ̀. Ọ̀rẹ́ mi àtàtà, kí lo fẹ́ kí n fún ẹ jẹ. Kí lò ń jẹ tó dà bí aràn yìí? Ibo ni ọkọ yí ń lọ? Ọjà ni mò ń lọ báyìíì o. Ẹran ọ̀sìn ni ewúrẹ́ àti adìyẹ. Wọ́n gbin ọ̀dọ̀dọ̀ sí àárín ọgbà ilé náà. Ẹ gbàdúrà kí ara wọn máa ní okun àti àláfíà. Mo járọ́ọ Láídé. B’ólóde ò kú, òde ò le wu gbẹ́gi. Nígbà tí a lọ síbẹ̀, a rí Awólọ́wọ̀ ní ìlú Ọ̀wọ̀. Gbogbo yàra ti sùn lọ. Ayọ̀mídé ti rí’ṣẹ́ sí ìlú ọba. Dókítà sọ pé àwọn oní gbèsè òun ò tíì sanwó. Ọlọ́run má jẹ ká r’ógun àìsàn. Èré orí ìtàgé ni iṣẹ́ tí Jídé Kòsókó ń ṣe. Orun ni Adébọ̀wálé sùn táa fi lọ táa fi dé. Olóorun ìyà. Ajíbádẹ ní òun ò lọ sí Kàdúná. Ó gbèjà àbúrò rẹ̀ gan. Bàbá àti màmá ti lọ sí òde òkú àwọn Ṣeun. Rántí jẹ ohun tí ẹ gbé kalẹ̀. Àwọn gángan ni apèèrè ọ̀rẹ́ kìtìtìtì àti ìyekàn kàtàkàtà. Ṣé o ní’fẹ mi tó bí mo ṣe ní’fẹ rẹ bí? Òògùn ilẹ̀ tútù ni wọ́n lò fún Ọlábìntán. Ibi ijà kan ní Kétu ni wọ́n ti fọ́ ojú ọmọ náà. Àwọn Yorùbá kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọrọ ọmọ bíbí láwùjọ. Lọ́jọ́ tí mo dé’lùú Ọba, ẹnú kọ̀ láti padé. Ẹ̀rọ ayárabíàṣá ni mo fi ṣe iṣẹ́ náà. Ẹyin tútù ló wà. Èdè ni ọ̀nà ìgbà báni-sọ̀rọ̀, èyí tí a fi ń gbé èrò-ọkàn wa jáde. Ìjọ kérúbù la ti jọ́sìn lọ́ṣẹ̀ tó kọjá. Ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ ni àwọn Táyọ̀. Àbá ni ikán ń dá, ikán ò le j’òkuta. Àwọn dókítà fẹ́ ṣe ìyanṣẹ́lódì f’ọ́jọ́ mẹ́ta. Ṣé alayé-lọ̀run ni ẹ́ ni tóo fi ń fọ́nu? Ilé ti sú mi, ibo ni a lè lọ? Wọ́n ti ń pè’run ní mọ́ṣáláṣí. Ògúnlájà fẹ́ran kí àwon èèyàn máa sa òun. Ẹ̀yin ará ẹ jọ̀wọ́, ìwé ìdánimọ̀ mi àtẹ̀yìnwá ní àwọn ìṣòro kan. Alákadá ni ọ̀gá rẹ̀. Ẹ ò gbodọ̀ dá ẹnikẹ́ni l’ẹ́bi. Báǹkì wo lò ń lò ná? Ohun gbogbo tí Ọlórun dá, dáradára ni. Aṣèyíówùú l’Ọlọ́run wa. Àwọn ẹ̀dá inú ìtàn lè jẹ́ ènìyàn tàbí ẹranko bí ajá, Ìjàpá, àti iwin. Wọ́n ti mú iná lọ kí n tó jí. Àfín ni ọko Ìyábọ̀. Ajá là n pa b’ọ̀gún. Fún mi ní ìdajì ìgò epo. Ìdun wà lórí ibùsùn Gbénga. Láti mú ọjọ́ ni wàhálà. Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ láti ilẹ̀ ló mú kí ayé mi ṣì gbádùn báyìí. Báwo ni ò bá ṣe dùn tó kí àwọn alágbára má fi agbára da èèyàn láàmú. Gbogbo àwọn ènìyàn náà ti lọ sí àárín ìlú. Báyọ̀ fi ọwọ́ gé fáànù. Kò sí epo nínú ẹ̀rọ ìdáná. Àpẹẹrẹ rere ni ó fi lé‘lẹ̀. Irun kọjúsọ́kọ ló gbé s’órí. Àdògán náà wà ní ẹ̀yìnkùlé. Àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn ti ń tako àwọn ìwé mímọ́. Ṣe bí o ti mọ, ẹlẹ́wàa Ṣàpọ́n. Àwọn kan sọ pé mi ò mọ oúnjẹ sè. Yọ ipin ojú ẹ kí o tó máa wo ti ẹlòmíràn. A ṣe àkíyèsí pé wàhálà yí ò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Wọ́n ti rí ọmọ Ìya Bọ̀dé gẹ́gẹ́ bí onírọ́. Ṣé o ṣì lè bímọ ṣá? Bí ènìyàn ṣe ń lo èdè bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹrankọ ní bí wọ́n ṣe máa ń bára wọn sọ̀rọ̀. Gba owó yìí kí o fi jẹun àárọ̀. Kò s’ẹ́ni tí ò ní kú, tí kò ní lọ s’ọ́run. Iṣẹ́ ni wón ń wá kiri. Àkìtàn ọ̀hún wà níwájú. Inú ilé ni mo bá ìyàwó kékeré tí wọ́n fẹ́ fún bàbá. Báwo la ṣe ń gbin ẹ̀gẹ́. Ìyàwó àti ẹbí sì ni wọ́n jogún gbogbo rẹ̀ fún. Ìbẹ́pẹ náà pọ̀n púpọ̀. Ẹ̀wọ̀n gbére ni wọ́n ju ọ̀daràn náà sí. Arómáṣọdún bímọ ọkùnrin làǹtilanti. Oò tiẹ̀ bẹ̀rù bí mo ṣe ga tó. Ìlúbìnrin ni wọ́n sọ pé àwọn ń lọ. Orí ń fọ́ mi láti oṣù kejì. Mo ní’fẹ́ aṣọ òkè. Ó wà lára àwọn ohun tí àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun ọ̀hún gbà lérò. Lọ bá mi ra owó sí orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi. Òun ni ẹni àkọ́kọ́ ti mo kọ ní ìfẹ́ sí. Wọ́n máa ń ṣe orò fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ j’̣ọba. Ẹ fún mi ní àsìkò díẹ̀ síi. Bàbá mi gbọ́ òyìnbó ṣùgbọ́n kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ọ́ sọ. Rájí ni òun fẹ́ kọ́’lé kí òun tó bí’mọ. Àágùn bọ́ lára rẹ̀. Lọ mú aṣọ ìbora fún Adúnmáradán. Aṣọ funfun méje ni ó sá sí ìta. Kíni a mọ Ọbásanjọ́ fún? Irú èyí ò lè ṣẹlẹ̀ ní’lu òkè rárá. Ẹ máa gbọ́ o, kẹ́ẹ bá wa dá síi. Mò ń lọ sí Apọ́ngbọ̀n. Ìwé márùn-ún la ma rà fún kọ́ọ̀sì náà. Rádaràda ni gbogbo eléyìí ń ṣe. Ó rẹ́rìín músẹ́. Ikú p’Abírí, Abírí ti kú. A máa ṣe tán kí oṣù tó parí. Rọra máa gbá èyàn jàre, ṣé ò mọ̀ pé ọwọ́ rẹ máa ń dùyan ni? Ẹ fún-un ní omi kó mu. Ẹran ìgbẹ́ ni ìgalà àti àgbọ̀nrín. Ọlọ́kọ́ ńlá ni bàbá àgbẹ̀ náà. Búrẹ́dì ni wón tà ní iwájú ṣọ́ọ̀ṣì yìí tẹ́lẹ̀. Mo máa bọ́’lè ní oríta-mẹ́rin yẹn o, ẹ jọ̀wọ́ ẹ rọra tẹná mọ́’kọ̀ o. Ó ti tóbi jù, mí ò lè gbée. Ẹnu ẹni la fi ń kọ mé jẹ. Ó figbe s’ẹ́nu pariwo. Kí Ọlọ́run má fi oúnjẹ wa síbi tó nira. Gẹ̀rẹ̀ tí wọ́n dé ọjà ni wọ́n rí wọn ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà. Ẹnu ọwá lọ́ ti ń dádé Ọba Èkó. Àṣejù ni irun àyà. Ká má baà jìyà la ṣe bí Májìyàgbé. Ohùn ìsàlẹ̀ ni wọ́n fi ń gbé orin náà jáde. Ọ̀gá mi ló kọ ìwé náà. Ṣùgbọ́n, mo já èso kan lórí igi. Láti jẹ́ ọkùnrin, iṣẹ́ ńlá ni. Lára àwọn ìlú tí ọdún Ọ̀sún ti gbélẹ̀ ni ìlú Ìrẹ̀, ìlú Ọ̀yọ́, ìlú Ìkírè, àti Ìlú Ìjẹ̀bú. Ẹní fẹ́ pẹ́ láyé, ṣé ojú rẹ̀ ò ní rí ibi? Ta lo yí ẹ̀rọ amúlẹ̀tutu sókè? Adìẹ ti yé ẹyin sílẹ̀. Ilé ilẹ̀ náà ti kún. Ọmọ náà dọ̀tí bí ẹlẹ́dẹ̀ igàn. Kò sí bí igimú alágbàro ṣe gùn tó ẹni tó gbéṣẹ́ fún lọ́gá. Ìjá bẹ́ sílẹ̀. Ìjọba yóò fi kún owó àwọn òṣìṣẹ́. Ilé ẹjọ́ ti tú ìgbéyàwó náà ká. Ṣé nítorí Ànọ́bi ni Ọlọ̀run ṣe dáa yín? Ọbá ti gbẹ́sẹ̀ lé ìyàwó Moróunfólú. Irun dúdú ni kìkì gbogbo ara olóńgbò náà. Ìjọba ìpínlẹ̀ ti tún ọ̀nà náà ṣe, ọ̀kan fún àlọ, ìkejì fún àbọ̀. Ọmọ bíbí ìlú èkó ni wọ́n pè ẹ́. Gbogbo ọmọ ìyá ìbejì ló ti bí’mọ. Mo rántí ìgbà èwe mi àti àwọn oun tí mo ṣe. Akin ti lọ ra súyà wá. Ọmọ pupa ni ó bí lẹ́yìn àkọ́bí ẹ̀. Ẹni rere ni alábàágbé mi ti mo sọ fún ẹ nípa ẹ̀. Ẹyẹlé funfun kìí bí dúdú. Pìrìgìdì ìyà ni wàá jẹ kúrò nídiìi ayò yìí lónìí. Àwọn tí wọ́n mọ ìtàn náà ò pọ̀ rárá. Àìsàn ti kọ lù wọ́n. Ó ti rẹ̀ wá sínú ọkọ̀ tí a wà, àti òwúrọ̀ ni ọkọ̀ náà ti ń wà wá kiri. Àgbò ni Mojí ń mú kiri. Ọmọ bọ̀dá Kofí ṣubú. Iyẹ̀pẹ̀ ló rọ sínú ike náà. Lára àwọn ìwé tí mo fẹ́ràn láti máa kà ní ìgba tí mo wà ní ilé ìwé girama ni. Ayọ̀dèjì ló fún wọn l’ówó. Ijó máa ń jẹyọ nínú rẹ̀. Àga irú èyí tí àwọn òyìnbó máa ń lò ni ó wà nílé Ọ̀túnba. Ibi o bá lọ ni mo máa wà. Táyà ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà bẹ́. Kí lo fẹ́ lọ ṣe nínú ilé tí ó ti wó? Gbogbo èyí ni mo ti ṣe fún ẹ, ǹjẹ́ ìwọ́ lè ṣe èyí fún mi? A ń sọ̀rọ̀ sí Ọrẹolúwa bí ẹni tí ò níran. A sọ fún-un, ṣùgbọ́n kò gbó. Ọ́rẹ́ mi má ṣe kánjú ju kádàrá. Àmídà ló kúrú jù ní kílàsì. Ibo ni wọ́n gbé àpótí náà sí. Ọdẹ náà pàdé iwin gẹ́gẹ́ bí ìtán ṣe sọ. Ọjà Ọba jẹ́ èyí tí à ń ná ní ọrọọrún. Ilé ìfowópamọ́ yapa nì àgbègbè Adéọlá Ọdẹ́kù. Ọmọ jayéjayé ni àwọn ọ̀rẹ́ mi. Adetìmí fẹ́ràn ìlu sákárà. Ìjọba ìbílẹ̀ ti ń tún àwọn ọ̀nà àdúgbò wa ṣe. Ìpàdé tí mo lọ lánàá, wọ́n pín owó n’íbẹ̀. Ọba gan ò rí ohun kọ̀kan ṣe sọ́rọ̀ ilẹ̀ yíì. Olúwa ọlọ́run, ọba atẹ́rere kárí ayé. O ṣé tí o rán mi létí. Àwámárììdí ni Olórun. Ó máa ń ni elégbè rẹ̀ lọ́dọ̀. Ẹyẹ abàmì ni ẹyẹ igún. Mi ò ní ìdáhùn sí ìbéérè náà. Mo y’ọjú wo àwọn àlejò náà l’átòkè. Ọ̀kẹ́rẹ́ náà sá gorí igi. Gẹ́gẹ́ bí ifá yìí ṣe ṣàlàyé, ire lojú owó ń rí. Kí a ní ìyàwó tó rẹwà kò ṣe pàtàkí tó èyí tó n’íwà. Ire owó ni mo yàn kó wọ’lé mi wá. Àwọn òṣìṣé ìjọba ti da’ṣé lẹ̀. Àgbà Alfa ni à ń pè ni Rájí. Wọ́n ti fi pamọ́ sínú ilé ìfowópamọ́. Ṣé iṣẹ́ lo fẹ́ kọ́ àbí ìwé lo fẹ́ kà? Kí ló lè fa kí ara máa ro èèyàn? Ẹlẹ́pa ìjẹ̀bú — èyí tí o fẹ́ràn gaan — wà ní ìtòsí. Ọ̀bọ́ bẹ́ lu ọmọ náà láti òkè. Ọlọ́run, ṣàánú fún wa lórí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí. Amúdá ò fẹ́ lọ kírun. Oríṣi obì tí a ní kò fi bẹ́ẹ̀ yé ọ̀pọ̀ ènìyàn láwùjọ wa lónìí. Ó ti wá hàn gbangba pé gbogbo ohun tí à ń ṣe ní àwùjọ ẹ̀dá pátápátá, eré-oníṣẹ́ ni gbogbo wọn. Bímpé ni mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ fún orílẹ̀-èdè wa. Orí ẹni ní ń mọ àtilà ẹni. Gèlè náà gbé ẹwà rẹ̀ jáde. Bàbá mi sọ ìtàn ìlú wa fún mi, pé láti Ìkọ̀tún la ti wá tẹ̀dó sí Ìrẹ́pọ̀ọ́dùn. Yìnyín náà pọ̀ jọjọ, ọ̀tútù ń mú. Ládúru gbogbo ìdojúkọ tí ó wà ní ọ̀nà wọn, wọ́n f’orí tìí dé òpin. Ó ti sá lọ, ọ̀rọ̀ náà kọjá ohun tí agbára rẹ ká. Ìkejà ò jì́nà sí Ọ̀pẹ̀bí. Ṣé o fẹ́ràn aṣọ tí ẹ̀gbọ́n rẹ fi ránṣẹ́ láti òkè òkun? Ọmọ méjì ni Simi sọ pé òun fé bí. Mo máa gbìyànjú láti ríi dájú pé o jìyà ẹ̀sẹ̀ rẹ. Ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà ni Mohammadu Buhari. Atá ti sá paá lórí. Bí èkùrọ́ ṣe jẹ́ alábákú ẹ̀wà bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ mi sí o. Ọláwùnmí jẹ́ ẹni tí ó ní ìrẹ̀l. Wọ́n pa Olúwa wa, ó sì jíǹde. Wọ́n kì ń fọnu fún ọmo ìkókó. Ojú rẹ̀ funfun, ó dà bí ẹni tí ara ẹ̀ kò yá. Ẹ wo ìdí ọ̀rọ̀ náà kí ẹ tó dájọ́. Ẹ̀gún gún ọmọ náà lẹ́sẹ̀. Balùwẹ̀ ni mo bọ́ sí tí mo ti ń jó. Ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run ni ó wà. Ọkàn mí wúwo púpọ̀. Kí ló lè mú kí orí máa fọ́ ni báyìí? Ọba òyìnbó kìí dé Adé rẹ̀ ní gbogbo ìgbà rárá. Màmá àgbà sọ fún Lájídé pé kó lọ gba àródan wá. Onígèlè yayaya ni màmá yẹn. Mo bẹ̀rù olóńgbò púpọ̀. Àlùfáà yín tuntun ti ṣiṣẹ̀ ní ìjọ wa rí. Ṣé ẹ ní dòdò àti ẹran? Èdè Gẹ̀ẹ́si ti di gbajúmọ̀ láàárín àwọn èdè àgbáyé. Àwọn bíríkìlà ń tún ilé náà ṣe. Ẹyẹ méjì ló wà lórí igi ọ̀pẹ. Ní ìrìn-àjò tí mo lọ, mo rí odò kan tí à ń pè ní odò aláró. Kò sí bí òǹkọ̀wé Yorùbá ṣe fẹ́ tẹ̀lẹ́ òfin àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ. Ìfẹ́ náà múmi lọ́kàn, mi ò rí oorun sùn. Nígbà tí ó di ọjọ́ keje, ilẹ̀ ṣú. Súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ pọ̀ ní ọ̀nà Ìkòròdú. Kò sí Iná lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi. Ọ̀pọ̀ ni ohun tí ó wà nípa ẹyẹ lékeléke tí a ò mọ̀. Kí ló dé ti ò kìí kan ilẹ̀kùn? Bí ọdẹ bá rò iṣẹ́ ro ìyà inú igbó, tí ó ló pa ẹran kò ní f’ẹ́ni kan jẹ. Mo fẹ́ kúrò ní gbogbo sàkánì tí wọ́n ti mọ̀ mí rí. Mi ò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ mí máa dàmú ẹ. Bí òní ti rí ọ̀la ò lè rí bẹ́ẹ̀. O ṣé tóo wá sí ’lé mi lónìí. Ọlọ́kadà ló gbá ọmọ wọn. Àwọn èyàn ló sọ fún nípa ìyàwó rẹ̀ tó ń s’ágbèrè. Adé ti lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá rè láti lọ fi àwọn nǹkan kan tó o létí. Tí kò bá kí ń ṣe ọ̀làjú tí ó ti gbinlẹ̀ l’Ékò ni, àwọn ìlú oko gán wà pa. Kí ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń da ọkàn rẹ rú? A máa ń rí ìjẹyọ ìlù lílù, ijó jíjó, ẹ̀fẹ̀ ṣís̀e, oríkì kíkì, èébú bíbú, ìkìlò ṣíṣe. Ọ̀tá yín ò ní sinmi lórúkọ Jésù. Ọkọ̀ ni bàba tóo lè bá sọ̀rọ̀ ní Surulere. A rí erinmí ní Ìjẹ̀bú nínu igbó. Ọ̀sán kan ṣoṣo ni ìṣẹ̀lẹ̀ yí ṣẹlẹ̀. Orí odó lo jókòó lé. Ó yí omi dà sínú ike mìíràn. Òwe lẹ ó máa pa, ẹ ò ní pà’nìyàn. Ẹ̀rọ amúlétutù náà ti bàjẹ́. Ìrèké jẹ́ èso tó dùn bíi ṣúgà. Mi ò nífẹ sí gbogbo ìkan wọ̀nyí. Ọbabìrin Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti pẹ́ lórí oyè gan ò. Ìsọkúsọ Àmọ́dù ti pọ̀ jù. Nígbà tí ọmọ yìí dàgbà, ó tọ́jú ilé àti ọgbà. Bàrúwá ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ríi pé ohun gbogbo lọ dédé. Lọ se ewédú ka lè fi jẹ àmàlà ní alẹ́. Nínú ọkọ̀ táa wọ̀ lọ s’Ọ́yọ̀ ọ́, èmi Adéyọọ́lá laá jọ jókòó. Àpótí tí mo sọnù kéré ju èyí tí mo gbé lọ s'ọ́jà lọ. Mo ṣàkíyèsí wípé ọmọ náà ní ìgbéraga. Agbọ́n ta Ṣubúọlá. Lára ibi tí a dé ni ọ̀dọ̀ Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́. Iṣẹ́ gèlè wíwé ni à ń ṣe. Gbé kọ́ọ́pù tí ó wà ní abẹ́ ibùsùn ẹ̀gbọ́n rẹ wá. Ẹ báwa s’àmín ẹ̀, oríi wa ò ní burú. Mo ti gbé omi sí ẹ̀yìn ilẹ̀kùn. Lára orúkọ tó gbajúmọ̀ ni Tinúbu ń jẹ́. Iṣu náà ti bàjẹ́. Kí wa ló tún kù tí ìyá Bọ̀dé ń wá káàkiri báyìí? Eegún ti wọnù ẹran, ẹrán sì ti wọnú eegun. A nílò ọgbà ńlá láti gbin àwọn èso náà. Ẹlẹ́nu bíi ti pẹ́pẹ́yẹ ni Tàmẹ̀dùn. Jùwọ́n ló gbà mí sílè nígbà tí wàhálà pọ̀ fún mi. Tí o bá rí ọkùnrin tí ó ń bá ẹ gbọ́ bùkátà díẹ̀, o jẹ́ má jẹ kó lọ mọ́ ẹ l’ọ́wọ́. Ohun tó ṣemí ní kàyéfi ni bí àwọn gẹ̀lẹ̀dẹ́ ṣe máa ń ní ìdí ńlá. Wọ́n rí ọmọ tuntun kan lórí ààtàn. Wọ́n na Fadérẹra ní ilé ìwé ọjọ ìsinmi. Pẹ̀lúmi pè mí láti dúpẹ́ oore. Àbẹ̀kẹ́ mu àgbo títí tí ó fi fẹ́ bì. Iṣẹ́ ìjọba ni ó wù mí láti ìgbà tí mo ti wà ní kékeré. Ẹnu-Ọwá ni bàbá kọ́’lé tuntun rẹ̀ sí. Ẹni tí ò gba kádàrá yóò gba kodoro. Ìmọ̀ ti fi yé wa pé Òrìṣa Ò gún ni àwọn alágbẹ̀dẹ. Ẹ̀sin mùsùlùmí ò fàyè sílẹ̀ fún ajá jíjẹ. Mo ò lọ sí ibìkankan pẹ̀lú ẹ. Gbogbo eyín Ìya Bọ̀dé ló ti yọ tán. Gbogbo wọn ni wọ́n ń forí balẹ̀ f'Ólúwa lati àárọ̀ di alẹ́. Mẹ́ta ni àwọn òṣèrè Ìjẹ̀ṣa tó ń gbé ilú yìí. Ẹ bu ẹmu díẹ̀ fún òun náà. Títà ni akekèé máa ń tani. Ọmọ ọ̀lẹ ò ṣeé yá ní tọ́rọ́. Ìyàwó ba oko rẹ̀ nínú jẹ́. Ó ja ọbẹ̀ sí aṣọ. Mò ń jáde lọ sí ibi iṣẹ́ láti lọ gba owó oṣù. Mo nífẹ sí àwọn orin Lágbájá. Ẹ̀fọ́rí ló kọ lùú. Àríkẹ́adé tún ti fẹ́rakù. Olúmòye sọ pe ìgbà tí òun bí ọkùnrin ni inú òun dùn jù. Pọ́n ara rẹ le kí o má baà kàb. Wọ́n ti gbé iṣẹ́ mìíràn fún mi. Géètì ilé-ìwé ni mo ti pàdé Sìlàmíyà ní àná. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní kí ilà ó tó di oge, ó ni ohun ojú rí. Ti ilẹ̀kùn kí o bá mi ní ojú ọ̀nà. Àwọn ọ̀rẹ́ Adéṣẹwà ó ń jowú rẹ̀ nítorí ẹni tó ń fẹ́ nísìyí ní owó púpọ̀. Nígbà tí a wà ní kékeré ìya Lábísí máa ń na ẹni tó bá súfe nínú ilé. Ẹ̀mí á ṣe púpọ̀ ọdún láyé. Láti ibo ni oko bàbá wọn ti bẹ̀rẹ̀? Bàbá àgbà, ṣé ẹ ti jí? Orógbó náà gbó keke. Akọ́lédowó ti kọ́lẹ́ alájà méje. Àtàrí àjànàkú ni ọ̀rọ̀ náà jẹ́, kìí ṣẹrù ọmọdé. A fẹ́ lọ wo eré ìtàgé ní Oríta Mẹ́rin. Ọmọ rere ni ẹ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kọ́ọ̀sì mẹ́wa ni wọ́n ní ká se. Ṣé dáadáa lo wá lásìkò yìí. Àwọn ohun amáyédẹrùn ti pọ̀ lóde. Ta ló ń dìtẹ̀ mọ́ Ọba wa Aláàfin. Ṣé ẹranko ni ikún ni? Mo gba ìpè oríireè kan láti ìlú òyìnbó. Ẹ kú ọjọ́ ìbí ooo, ọ̀jọ̀gbọ́n Ṣóyínká. Abọ́ wà nínú korobá náà. Báwo ni mo ṣe fẹ́ parí iṣẹ́ yìí na? Wọ́n ti lé àwọn ẹbí Ayọ̀bámi kúrò ní agboolé. Ẹ́sítérì máa ń hùwà òmùgọ̀. Ṣé bí à ṣe dúdú náà ni ọpọlọ wa ṣe dúdú ni? Ó dà bí ẹni pé ó ti rẹ olùkọ́ọ wa. Ọmọ yìí ò ní àpọ́nlé kankan rárá. Dáadáa ló yẹ ká máa ṣe. Ààrẹ orílẹ̀ èdè ń bọ̀ ní Civic Ceter ní ọ̀la òde yìí. Aṣọ títà ni iṣẹ́ ìya Bùkọ́lá. Àwọn ìjọba ni wọ́n gbẹ́ ibi ìpọnmi náà. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní, “Kò sí bí a ó ṣe se ebòlò tí kò ní run ìgbẹ́.” Lára àwọn olùkọ́ tí mo ò le gbàbé ni ọmọ̀wé Shèyí Kenny. Orúkọ fífúnni kìí ṣe ohun yẹpẹrẹ, bẹ́ẹ̀ kì í ṣe bàbàrà tó bẹ́ẹ̀. Adéyinká sọ pé òun ò lè jẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa ku akókò òun dànù bí èlùbọ́. Ṣé o ti gbọ́ nípa ọdún òkè ìtàsẹ́ rí? Ilé ayé gba jẹ́jẹ́ ni bàbá máa ń sọ. Ìlù Àyándélé ń ró kókó. Dígí tí a gbé sí balùwẹ̀ ti fọ́ ní àná. Ẹsẹ̀ ẹran náà ti kán. Ra àgbálùmọ́ fún mi tí o bá ń bọ̀. Omi adágún kan wà ní ẹ̀yìn ilé-ìwé mi. Lọ fi otí pa ìrònú rẹ́. Adájọ́ dáa lébi ẹ̀sùn táa fi kàn-án. Orísìírísìí ìgbésẹ̀ ni ó máa ń jẹyọ nínú Ọdún Ifá. Wọ́n ń fá irun ara òkú náà. Tóo bá dé oko àwọn Àkànmú, wàá fẹ́ràn iṣẹ́ àgbẹ̀. Adéẹ̀kọ́ ní òun nífẹ omi ju ọtí lọ. Ṣọ̀pọ̀ná ò ní mọ ‘lé wa o. Àmin. Ariwo yín ti pọ̀ jù. Àwọn ọmọ aráyé ò kí ní sùúrù. Ṣé àwọn ọmọ yín mọ òòṣà tí wọ́n ń pè ní ìgunnu? Ìrẹsì àti ẹ̀wà ni oúnjẹ tí mo fẹ́ràn jù. Aṣọ ìbora wọn dà ná; níbo ni wọ́n fi sí? Ẹ jẹ́ kí a dá ara wa ní ara yá. Èèwọ̀ Orìṣà, ilẹ̀ ò ní ṣú mọ́ olóore. Àmì ayò mẹ́ta sí méjì ni Sàlámì fi na Sàláwà. Ká máa gbàdúrà tí a bá jí dára púpọ̀. Ìdí ọkọ̀ ni mo gbé ẹrù lọ ní àná nígbà tí ọkọ̀ gbá ajá àwọn màmá. A fẹ́ ṣe ìṣàfihàn àwọn ohun abẹ̀mí nínú litírésọ̀ Yorùbá. Ilé alájà méjì mẹ́ta, ọkọ̀ mẹ́rin, àti oko kòkó kan ni gbogbo dúkìá tí ó fi sílẹ́ lọ. Àwọn ará ìlú ní ìgbàgbọ́ pé ọ̀nà èrú ni ọba tuntun yí fi d’órí àléfà. Tájù àti Tọ́lá ń lọ sí Àkúrẹ́ ní ọ̀la. Olùṣọ́gbà ni iṣẹ́ tí mo bá ẹ rí. Ọtí ẹlérìn dòdò ni wọ́n fi ṣe mí lálejò ní’bi òde ìyàwó tí mo lọ. Ṣé ki n wá gba kiníyẹn ni? Ẹ jẹ́ ká ṣeré nínú òjò. Wọ́n ti gbée lọ sí Ibojì. Èmi nìkan ni mo sun yàrá mọ́’jú. Ọmọ yìí fẹ́ fi ijó ṣe mí léṣe. Àyọnusọ Fàlí ti pọ̀ jù. Ìsèkúsè ni àwọn olópàá máa ń sè fún wa. Òun ló tọ́ sí láti máa sọ̀rọ̀. Kọ́kọ́rọ́ mọ́tò bàba Fáuśa ni àwọn ọmọ yíì fi ń ṣeré. Gaàrí yẹn ti wú tó bó ṣe yẹ. Yóò dára fún ẹ, mo dúpé púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ. Mo fẹ́ran ilé ìtura náà. Àti ìjẹrin la ti ri’ra gbẹ̀yin. Ìyẹn ni pé àwọn ìlú kékèké nínú igbó yìí náà máa ń lo iná ìjọba. Ilé rere ni wọ́n ti wá. Yèyé mi a máa bínú ní ọ̀pọ̀ ìgbà lórí ohun tí kò tó nǹkan. Bọ̀dá mi yóò mú mi lọ sí ìlú òyìnbó nígbà tó bá ń padà lọ. Ilẹ̀ ti mọ́ bá àwọn ọ̀daràn yẹn. Ó sì tún jẹ ẹ̀bùn pàtàkì láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè. Bọ́lá máa ń ṣe ìrànrán tí kò bá tètè sùn. Àrẹ̀mú ló ṣíṣẹ́ náà, ó ṣì ṣee dáadáa. Àìgbọ́fá là ń wò’kè, ifá kan ò sí ní párá. Kí ló dé tí o wà nínú àhámọ́ Bí oò ti ẹ̀ jẹ́ kó hàn ní ojú ẹ, mo mọ̀ pé ohun tí wọ́n ṣe dùn ẹ́ gidi. Bí babaláwo náà ṣẹ̀ gba ibẹ̀ kọjá ni. Yọ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ kúrò nínú iná. Àwọn ẹranko wo ló máa ń jẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀? Ọmọ mí ti pé oṣù mẹ́jo, ó sì ní eyín kan. Ọládèjọ kú ikú akin. Wọ́n ti da ìdọ̀tí sọ́nà lẹ́ẹ̀kansíi. Bá mi jìṣẹ́ fún bàbá wa. Gbogbo ìgbìyànjú mi ò gbọdọ̀ já s’ásán. Ó ṣeéṣe kí ọmọ ẹ̀gbọ́n wá pá lórí bíi bàbá rẹ̀. Èyí já sí pé, gbogbo ìmọ̀ pátá ló ń bẹ nínú ifá. Ẹran ọ̀sìn ni àgùntàn, ewúrẹ́, òbúkọ, ẹlẹ́dẹ̀ àti màálù. Ṣé o lè rìn kíá ju báyi lọ? Aya rere l’ódèdè ọkọ ni Ṣọlá. Ẹ ṣàdúà kí ikú dáwọ́ ibi rẹ̀ dúró. Lọ mú àtòrì wá l’ẹ́yìn ilẹ̀kùn. Èébì ń gbé ìyá olóyún yẹn. Mo ní’fẹ láti bá wọn lọ fún ìnáwó náà. Èjì bí èjì l’àgbà ń tayò. Eré orí ìtàgé náà yo lárinrin púpọ̀. Ọmọ iṣẹ́ méjì ló wà ní ibi iṣẹ́ yin. Tolúwa ni ilẹ̀ àti ẹ̀kún rẹ̀. Ìlẹ̀kẹ̀ mẹ́ta ló wà lọ́run Ọba. Àwọn ẹlòmíì ò ní ìtẹ́lọ́rùn rárá. Oríṣi bàtà méje ni màmá mi ńi. Kókó àti àkàrà la fẹ́ jẹ lónìí. Adébámbọ̀ mú àfẹ́sọ́nà rẹ̀ wá s’ọ́dọ̀ ìyá àgbà. Farabalẹ̀ kí o gbóhùn wọn. Àgbọn wà ní orí igi náà. Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ìwé náà ló mọ̀wé. Ògúndípẹ̀ ni ọ̀gá wa. Odidi oṣù mẹ́ta ni àwọn ará ilé wa yóò fi gba ìsimi lọ sí òkè òkun. Báwo ni wàá ṣe máa da ilẹ̀ sí ojú àgbàrá báyìí? Kọ́lá ti fi ẹsẹ̀ gún ìṣó. Wọ́n rí àjẹ́ kan l’ọ́san gangan n’íbàdàn. Ogun ni ìlú yìí wà ní òní bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń fẹ́ kí gbogbo ayé rò pé àlááfíà ni. Ìròyìn agogo mẹ́sàn-án àṣálẹ́ ni bàbá ń gbó l’ọ́wọ́. Yà sí apá ọ̀tún tí o bá dé Òpópónà Ìṣẹri. Ẹja méjì ni wọ́n fi mu gààrí. Ẹ wo omi tó sọ póun ò ní bá ẹja rẹ́, àṣé omi ọ̀hún ni yóò ṣekú pẹ́ja. Gbogbo ohun tí mo fẹ́ ni wọ́n ṣe fún mi. Ẹ má tẹ̀ẹ́wọ́ mọ́. Olúwa, màá ṣe ìgbọràn. Àánú ni mo tọrọ. Kájọlà ni ibùsọ̀ táa ma kọ́kọ́ kàn ka tó dé Káṣọpẹ́. Fìlà náà dára lórí rẹ. Sọ ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ìwà ìbàjẹ́ nínú àwùjọ. Ìdí Àràbà ni Ìyálọ́jà ń gbé. Àgbàlá Bàbá Fọlákẹ́ ni àwọn ọmọ ti máa ń ṣ’eré ní ìrọ̀lẹ́. Túwó ni wọ́n sè fún wa. Ó bi bàbá rẹ̀ bí òún bá lè tan ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán náà. Òfin ìjọba ò jẹ́ kí àwọn oníṣòwò jèrè rárá. Ilẹ̀kùn ilé náà ti bàjẹ́. Òrìṣà, bó ò le gbèmí ṣe mí bó o ti bámi. Èròjà tí a fẹ́ fi se ọbẹ̀ kò tí ì pé o. Ìwádìí fi hàn pé Ò gún ni ẹni àkókò tí ó ṣe ọ̀rò ìṣípa òde ní ìlú Ìrè. Orísìírísìí ìgbésẹ̀ la máa ń gbé lórí ọ̀rọ̀ yìí. Adémìlúyìí ni orúkọ tí a fẹ́ mọ ọmọ náà sí. Láfún loúnjẹ wọn nílé Àl̀àkẹ́. Àdùkẹ́ ti sanra ju ọjọ́ orí rẹ̀ lọ. Nítorí àwọn ìbéèrè pàtàkì nìkan là ń gbà sílẹ̀ kí ilẹ̀ tó ṣú. Ṣé o ti rí abọ́ ẹlẹ́ta rí? Òkè ni ẹyẹ ti máa ń fò. Ní ọjà Èjìgbòmẹkùn ni a ti ra àwọn èso ọ̀hún. Ta ló wà nínú ọjà náà? Ipò wo lo dì mú nínú ilé iṣẹ́ náà? Mo ti fi ìgbà kan ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ojúṣe àwọn olùkọ́ ni láti ríi dájú pé àwọn ọmọ tí wọn kọ́ ní òye kíkún nípa iṣẹ́ ohùn. Oríṣi bàtà kan ni àwọn ọmọ ìyá náà rà. Ilé olókè mẹ́rin ni wọ́n kọ́. Ẹkùn lè ṣe ìnàkí léṣe. Alákọrí ni Àkànbí tó k’àkànpọ̀ nínú ooru. Mo ya ìwé náà sí méjì nítorí inú bí mi gidigidi. Mo ti rí ìdí tí kò fi yẹ kí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi ni. Àdùké kò ní pẹ́ gboyè ìmọ̀ nínú òfin. Ṣé kí a fún àwọn agbasọfọ̀? Ẹsẹ̀ ń ro ó púpọ̀. Ẹ jẹ́ ká sùn díẹ̀, ṣùgbọ́n oorun ò kùn mí. Iyá ọba náà tún wà níbẹ̀. Ṣe o ti rí ìdí tí kò fi lè tètè ní ọ̀rẹ́kùnrin. Òun àti ìyekan rẹ̀ ni wọ́n ń pariwo l’óru. Adébọ̀wálé sọ pé òun ò mọ̀ bí aṣọ òun ṣe sọnù. Màmá rán mi kí n lọ ra ẹja díndín wá ní ìsọdá. Òjó lọ ilé ní àná láti lọ mú owó ẹ̀ wá. Tùràrí olóòórùn dídùn ni wọ́n fi sí ibi ìtẹ́ òkú. Ojú ò ní tìyín lágbára ọlọ́run. Iṣu àti ẹyin ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ tán. Aṣọ híhun jẹ́ iṣẹ́ kan tí àwọn obìnrin yàn láàyò ní ìlú wa. Adéforítì ní ìforítì. Sáyídì ń ta Láfún ní agbègbè Ìta Àdó. Gìgísẹ̀ ọmọ naà ló ṣe léṣe. Mo ti gbìyànjú ohun tí mo lè dá lárà. Ebi ń pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n o. Èní ni màmá Kọ́ládé yóò fi ilé ìwòsàn sílẹ̀. Mi ò mọ ẹyẹ tó ṣu Adébóyè. Yàrá ìgbàlejò náà tóbi. Ọmọ mẹ́rin ni ẹran náà bí. Ìmọ́tótó borí ààrùn mọ́lẹ̀ bí ọyẹ́ ṣe ń borí ooru. Àdúgbò náà máa ń dákẹ́ rọ́rọ́. Olórí ilé aṣòfin wà ní agbègbè náà. Ọmọ náà gbé orí mi sí àyà rẹ. Wàyí o, kí a máa rántí pé gbogbo ohun táa bá ṣe la ma ká nikẹhìn. Áà! inú òjò l’àwọn omọ yí ti ń ṣeré. Ní ayé àtijọ́, àwọn bàbá ni wọ́n máa ń sába ṣiṣẹ́. Ìbọn ló bàá l’ẹ́sẹ̀. 'Ayé dùn-ún jẹ juùyà lọ' ni ọ̀rọ̀ tó bọ́ lẹ́nu Ṣùbòmí nígbà tó jẹ àmàlà tán. Wọ́n ti dée ládé ọba. Wọ́n ní kí a mú àkòrí iṣẹ́ ìwádi àṣekágbá wa wá. À ń lùú, ó ń dun. Ọpẹ́ ló yẹ wá. Ọmọbìrin náà rẹwà púpọ̀, tẹ̀gàn ló kù. Ọmọ bùjẹbùdànù l’Àrẹ̀mú. Àrèó máa ń fi ìwà tútù tanijẹ. Kìí ṣe gbogbo ènìyàn ló mọ ìtúmọ̀ orúkọ mi àfi àwọn tó ní ìmọ̀ tó jíire nípa orúkọ. Ojú Ọlọ́bùn ni ilé ìjọsìn àwọn Tósìn wà. Ìyá náà pàdánù ọmọ rẹ̀ láàárín ọdún kan. Kò yé mi o, ṣé Oshòdì lo wà? Ẹ̀jẹ̀ ń yọ ní etí ẹ. Ọ̀gẹ̀dẹ̀ inú ọgbà bàbá dùn púpọ̀. Mo kí wọn pé a kú ojúmọ́. Ògúntádé ni ó gba ìwé náà wọlé. Ìyá wa ṣe àkíyèsí ìwà ìmele Ọmọṣẹwà, ó sì ti pè ẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà láti bá sọ̀rọ̀ ní ìjìnlẹ̀. Kìí ṣe awọn ọmọlóòkú nìkan ni o ti ṣe ní àǹfàní tipẹ́tipẹ́. Ìjàpá gbọ́n gan nínú àwọn ìtàn Yorùbá. A ò ní rìn ní ọjọ́ tí ebí ń pa ọ̀nà. Gbà gbà gbà lọkọ̀ ń dún lóríi títì. Àwọn ilé alájà ńlá ńlá ló wà ní ọ̀nà ibiṣẹ́ bàbá mi. Mọ fẹ́ràn ẹlẹ́dẹ̀. Kí ló dé tò ń pè mí lánàá? Ẹwà rẹ pàápàá sì ṣe rẹ́gí bí ìdodo ẹ̀fọn. Bàtà tuntun náà wọ́n jọjọ. Arẹ́gbẹ́ṣọlá ti di ògbóǹtarìgì ọ̀ta nínú ayò ọlọ́pọ́n títa ò. Ojú abẹ́rẹ́ náà ṣì ń dùn-ún. Àǹkárá olójúméje ni Ṣaléwá wọ̀. Adìyẹ àti pẹ́pẹ́yẹ ni wọ́n kan pákó náà fún. Gbogbo àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú àwùjọ ní wọ́n lò láti fi ṣe àgbékalè eré àgbéléwò. A ó pàdé nílé ẹjọ́ tàbí àgọ́ ọlọ́pàá. Èmi àti ẹ̀ jà kúrò ni ṣùgbọ́n a ti yanjú ọ̀rọ̀ náà báyìí. Akíntópé kì í ṣẹgbẹ́ẹ Ọládìjì rárá. Àjàlá òun Àyìnlá ti ń ṣe ọ̀rẹ́ láti ìgbà kékeré wọn, inú agbolé kan ni wọ́n bí wọn sí. Àkìtàn ni gbogbo àdúgbò náà ní ayé ìgbà kan. Ìjẹta ni òjó rọ̀ kẹ́yìn. Inúu Fáṣọpẹ́ ń bí mi. Àwọn olè ja ilé ìfowópamọ́ náà. Ilé epo náà tóbi, ẹ̀bá ọ̀nà ló wà. Lára ìlú tó wà ní ẹkùn Ìlà-Oòrùn Àríwá ni Adamawa àti Bauchi. Ọ̀rọ̀ kátikàti wo lò ń sọ gan ná. Ìrìn àjò yí lárinrin láìní àwọn kọ́núukọ́họ kàǹkan. Mo fẹ́ lọ rí ọ̀rẹ́ mi kan ní ẹ̀yìn odi. Ẹ̀gbọ́n mi ò sí nílé o, ẹ padà wá nírọ̀lẹ́. Ó pọn dandan láti rán wa létí pé Káàárọ̀ Oò Jíire ni wá. Mo wá ṣe bí àdán orí igi tó so ara rẹ̀ rọ̀ bí ẹni tó ń tòògbé. Àwọn méjì ń jà lójú títì. Ṣé o mọ ìdí tí mo fi sọ bẹ́ ẹ̀? Adéwálé gbé egbòogi olóró wo ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ó ṣèṣì kọ iye owó tó ju iyé tí ó ná lọ. Abẹ́ igi ọdán ni bàbá ti ń jayé. Àwọn ọmọge mẹ́fà ni wọ́n ń jó ń gbìyànjú papọ̀. Mo nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí mi púpọ̀. Níkẹ gbé omi sí Àdèyí lẹ́nu. Ewúrẹ́ ń jẹ koríko. Ayé fẹ̀ ju òṣùpá lọ nítòótọ́. Mò ń ṣe iṣẹ́ mi dáadáa. Ìlú Ìlọrin ní àwon olorin dadakùádà wọ́pọ̀ sí. Aṣọ púpọ̀ ló wà lọ́jà, lọ ra tì ẹ. Jẹ́ ka fi bọ̀lì ṣe oúnjẹ ọ̀sán. Ṣé wàá jẹ́ bàbá àwọn ọmọ mi? Lọ ra èlùbọ́ wa lọ́dọ Ìya Mọ́ríá. Òjò náà rọ̀ ó fẹ́rẹ̀ hu òkú ọ̀l Òwú dúdú lowó iná. Ó fẹ́ dì mọ́ọ lát’ẹ̀yìn. Wọ́n sá eré àsápájúdé. Ní ilẹ̀ Yorùbá, bàbá ni olórí ilé. Ẹwọ̀n egbére ni a dá fun Aníní. Ta ló gbé aṣọ tútù sí ibí? Àwọn kọ́ọ̀sì yí dára gan o. Sàfúrátù ti gbé obì wá fún bàbá. Gbogbo ènìyàn ni ó ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira. Mo ní ìgbáfẹ́ ní agogo mẹ́san alẹ́. Wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé òhún ni. Ẹlẹ́nu bótobòto, a ó ma wírú yó ma wírù. Orí páànù ilé àwọn Ajírébi ni adìẹ náà fò sí. Ìjà náà bẹ́ sílẹ̀ nìgbà tí awakọ̀ kọ̀ láti wa ọkọ rẹ̀ kúrò lójúu pópó. Bíọ́dún kìí ṣọ́ owó náà rárá, ó lè ná gbogbo owó oṣù rẹ̀ tán ní ọjọ́ kan. I Ilé kan wà ní Ìkòyí tí mo máa ń rí, mo fẹ́ràn ìgbékalẹ̀ rẹ̀ púpọ̀. Yànmúyańmú ń kùn sí mi létí. Ìjàm̀bá ọkọ̀ òfurufú tó ṣẹlẹ̀ níjọ́sí ò tíì lọ lórí àwọn ènìyàn. Òkè kẹta ni àwọn Bánkẹ́ ń gbé. Màá ṣe iṣẹ́ náà nítorí ó dá lé orí àwọn ìwée Fágúnwà. Gàní ti mú kọ́kọ́rọ́ lọ. Ìníolúwa ti di sisí ọmọge. Ṣé o ti ṣe iṣẹ́ àmúrelé rẹ? Ìníolúwa ni orúkọ ọmọ àbúrò ìyàwó mi. Ọmọ dada ni mí látijọ́. Ṣé o ti tọrọ àforíjì? Ṣé mo jọ òmùgọ̀ ni? Ara rẹ̀ kìí lélẹ̀ tó bá ti wà lẹ́gbẹ ìyàwó rẹ̀ kejì. Àkèré fi inú ṣe ọgbọ́n ni wọ́n ń pèé. Ìrèti ń bẹ, bí ẹ̀mí bá ti wà. Ìgéraga Gbénga ga tó bẹ́ẹ̀ jẹ́ pé kìí fẹ́ ba ẹnikéni sọ̀rọ̀. Àdúrà gbogbo òbí ni kí ọmọ wọ́n ṣ’oríire. A lọ s’éjìgbò ní’jọ̀ọ́sí. Àgbantara ni bàbá àgbà fi máa ń nara ní abẹ́ igi ọsàn. Alọ́ba fi ewé wé ọṣẹ náà. Adémọ́lá nìkan ni ẹni tó mọ̀ ẹ̀dùn ọkàn mi. Àafin ọba náà ti kéré jù. Ọwọ́ mi ni kẹ́ẹ wò. Mo nífẹ̀ẹ́ ẹyin ojú rẹ̀. Á ṣeé ṣe lágbára ọlọ́run. Alábòsí ni wọ́n, àfàìmọ̀ kí ìṣe burúkú náà má bá wọn dàgbà. Ó dá mi lójú pé mo mọ iṣẹ́ náà ṣe. Lọ tẹ́ ibùsùn bàbá. Kí èdùmàrè dá èmí sí. Gbogbo rẹ̀ ṣẹ̀ hàn kedere sí mi ni. Ẹlẹ́nu wèrèpè ni mo pèé. Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa kìí yẹ̀ láéláé. Wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí Ifá ṣe wí. A ò ní gbà, ó ti hàn pé ẹ ti pàdé ọrẹ́ yín lọ́nà. Nígbà mìíràn, tí ìfẹ́ bá pọ̀jù, kò dára. Faransé ló gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé bọ́ọ̀lù ní ọdùn tó kọjá. Ṣòkòto Ọláànipẹ̀kún ò balẹ̀. Kí ló dé tí àwọn kan ma ń bínú tí wọ́n bá̀ ṣàpèjú wọn gẹ́gẹ́ bí i ènìyàn sísanra? Àwọn ìjọba ti ń da ọ̀dà sí títì ìlú wa. Ṣé o ti rí ilé kòkó ní Ìbàdàn rí? Ilẹ̀kùn méjì ni ó wà lọ́nà ọ̀run. Ire ló yẹ ní ṣíṣe, ìkà kọ́. Igi náà rí ràbàtà. Ẹni orí yọ, ó d’ilé. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà rẹwà púpọ̀. Ó ti y’óhùn padà. Àwọn ọmọ náà ti bàlágà láti lọ́kọ. Wàhálà tí àwọn ènìyàn ṣe láti lè jẹ́ ènìyàn láyé kìí ṣe kèrémí o. Wọ́n n bá ara wọn sọ̀rọ̀ lówelówe. Ọ̀rúnmìlà nìkan ló gbọ́ ohùn ẹnu Olódùmarè yékéyéke. Àwọn adájọ́ mẹ́sàn-an ni wọ́n dá ẹjọ́ náà. Àyìnlá ní Kúnlé fẹ́ràn obìnrin, ṣé ọkùnrin ni kó kwá fẹ́ràn ni? Àwọn Túnjí ti pààrọ̀ ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán wọn. Àyànmọ́ ò gbó’gun, ṣùgbọ́n ó gbọ́ àdúrà. Yin Olúwa ìwọ ọkàn mi kì o má ṣì ṣe gbàgbé ore rè. Ìjọba àpapọ̀ ti ṣe ìgbéga fún àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ ìròyìn kan. Ilé ẹ̀kọ́ girama tó wà ní Jíbówú ni Akíntádé ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Afẹ́fẹ́ náà pò ju kí èyàn bọ́ aṣọ sílẹ̀ lọ. Lára ẹbí tó gbajúmọ̀ ní ìlú Ìlọrin ni Sàràkí. Igbó lótun lósì, àwọn ilẹ̀ náà yóò wúlò fún ìjọba lọ́jọ́ iwájú, àbí kí lẹ rọ̀? Iṣẹ́ alágbẹ̀dẹ ni bàbá mi yàn láàyò. Ṣé o máa ń mutí? Fáànù mẹ́ta ló wà nínú yàrá ìgbàlejò. Ìfọ́tí olóyì ni mo fún ọmọ tí ó wà lẹ́gbẹ ọ̀tún mi lójú àlá rẹ̀. Ọ̀mọ̀wé fún ọmọ náà ní ẹ̀bun rẹpẹtẹ. Àṣáró elépo rẹ́dẹ́rẹ́dẹ́ ni mo bá nígbà tí mo ti Ibi’ṣẹ́ dé. Àwọn mìíràn ri obìrin gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tó nífẹ sí ohun ọ̀fẹ́. Ọwọ́ méjì ni wọ́n kó sí inú ẹ̀. Babájídé ni adájọ́ ilé ẹjọ́ gíga tuntun tó wà ní Ìkòyí. Wọ́n ti fi jọba Ìlú Alábà. Oyè Balógun ni idílé náà máa ń jẹ láti ìgbà yìí wá. Ọ̀rúnmìlà sọ fún Ògún pé Ìrémọjẹ ni a ó máa pe orúkọ orin arò yìí. Olúwa ọba o ṣé o, mo rí isó só bẹ́ẹ̀ ni mo rí ìtọ̀ tọ̀. Èmi àti àwọn àbúrò mi la sun yàrá mọ́’jú. Láti ìlú Àjàṣẹ́ ni màmá ti wá. Mo fẹ́ràn àwọn ọ̀rẹ́ mi. Kí Ọlóṛun mú ìgbà padà bọ̀ sí’pò. Wàhálà ọmọ yìí ò ní ṣ'ekú pa ẹ́ lórúkọ Jésù. Ilée wa ni mo wà nígbà yẹn. Ìyálé mi ti ẹ̀ bá wa lálejò lọ́sè tó kọjá. Òpẹ́bí ni àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti lọ ń ṣeré. Àwọn elétò ìlera ló ń se ìtójú fún àwọn aláàárẹ̀. Ní ọ̀nà àkọ́kọ́, wọn ò lè ní ạ̀wọn ò ní gba ti wa. Ọ̀gá ọlọ́pàá náà ló gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Ìjàkùmọ̀ kìí rìn’de ọ̀sán. Sùúrùlérè ni ibi tí a ó ti ṣe ìpàdé ọ̀sẹ̀ tó n bọ̀. Olójú dúdú ni wá tẹ́lẹ̀. Òkèfúnwa ti pinu láti ríi pé gbogbo ohun tí a nílò la máa rí gbà. Iṣẹ́ àmúrelé tí olùkọ́ àgbà fún wa yìí le gan o. Nígbà wo lò ń padà lọ sí ìlú yín náà? Àdùkẹ́ ń ta Mọ́sà ní àdúgbò kan ní Olúwọlé. Ẹ yí fáànù náà sókè. Irun àgbọ̀n mí ti pọ̀ jù. Ohùn wa ti há. Bí bàbá bá ń rìnrìn àjò, kí wọ́n má gbé àtùpà dání. Gọ́tà náà ń rùn. Ogun jà ní ìlú náà fún ọdún méje. Kí ni ká fi ṣe yín l’álejò báyìí, ṣé ẹ ó jẹ àmàlà tàbí iyán ni ká gún? Ìréde òru ti àwọn ọ̀dọ́mọge ìsẹ̀yín rawọ́ lè má wàá ti peléke síi. Wọ́n ti lọ fọ’bọ́ níta. Àárò Wọnúọlá sọ̀ mí. Lára àwọn agbẹjọ́rò àgbà ni Fálànà wà. Nígbà tí bàbá lọ sí oko ní ijọ́ kan ló rí ọmọ ìkókó náà ní abẹ́ igi ọsàn. Ẹ rora sáré l’ójú ọ̀nà. Iṣẹ́ ajé ló s’ọmọ nù bí òkò. Oyín ta á, ó sì sá lọ. Mo ti fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí alága lórí ọ̀rọ̀ owó orí tí a fẹ́ san. Fálétí ti lọ ra àwọn ṣòkòtò ní ọjà Èjìgbò. Ọ̀gá akọrin wa féraǹ mi gidi. Ẹ̀dá kan wáyé nípasẹ̀ àwọn méjì tí wọ́n sùn papọ̀, tí wọ́n sùn ì lóyún rẹ̀. Lọ gba kọ́kọ́rọ́ wá. Bàbá yẹn kìí gbọ́ràn, àfi’ìgbà tó bá súu. Ó ṣẹ̀ rí’ṣẹ́ mìíràn ni. Mo ti rí àwọn àbúrò mi á ti tó ọdún márùn-ún. Àgbò náà sanra. Ìsàlè àpótí ni màmá máa ń kó àwọn aṣọ olówó iyebíye wọn sí. Iṣẹ́ alágbẹ̀dẹ ni ó yàn láyò. Atọ̀ọ́lé ni ọmọ náà. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní agbára jọjọ, ó fẹ́rẹ̀ da àárín gbogbo ebí rú. Ó le kú, ìjà ọ̀rẹ́. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ ò ní aṣojú mó ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Ọdẹ àdẹ́dọ̀ ni Ọdẹ́wálé jẹ́ nígbà èwe rẹ̀. Bó bá wu Ẹyíòwùnmí, kó má da ẹran lọ sínú igbó. Fún mi ní ẹran àti ẹja jẹ. Ilésanmí dùn ju oyè lọ. Àdàkọ ni gbogbo wọ́n ṣe. Ta ló wà nínú ọgbà náà? Ó f’ọwọ́ lérán ó ń wò’ṣe olúwa. Òde méjì ni a ní láti dé. Hósítẹ̀lì rẹ ló ti gbé oúnjẹ fún mi. Mo gbà fún ọ̀gá mi , àlá rere ni wọ́n ní. Ẹ̀yà Yorùbá ti kúrò lẹ́gbẹ́ àwọn ẹ̀yà tí wọ́n máa ń ṣe àmúlò ìlànà òǹkà àwọn èdè mìíràn. Ojọ́ mẹ́wa ni ó kù kí a kásẹ̀ gbogbo ètò nílẹ̀. Lẹ́báa títì ni a ti rí atọ́kọ̀sẹ tí ń yẹ ọkọ̀ kan wò. Ẹ máa sọ̀dí wùkẹ̀wụ̀kẹ̀. Ọmọ yìí fi ewúrẹ́ rúbọ bí babalawo ti sọ fún un. Ọmọ yẹn ní ẹwà. Àra mí ń kóná ní ooru m’ọ́jú, ọpẹ́lọpẹ́ Ṣayọ̀ tó tọ́jú mi. Kòkòrò àárùn tí kò gbóògun ti pọ̀ ní ìlú yìí. Ilé tí èmi àti àwọn akẹgbẹ́ mi dé sí rẹwà púpọ̀, ọ̀rọ̀ gan kò lè ṣàpèjúwe rẹ̀. Ikọ́ burúkú wo ni ò ń wú báyìí. Ọ̀jọ̀gbọ́n lọmọ náà. Mo ò dára nínú eré bọ́ọ̀lù gbígbá. Ó rò pé màá fi orí lé ọ̀nà ìlà-ọ̀run padà lọsí ilé lọ sùn fún ọjọ́ díẹ̀. Bí kò bá sí èdè kò ní sí ìtakùrọ̀sọ láàárín ọmọ ẹ̀dá ádámọ̀ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọmọkọ́mọ ni Dèjì. Àpò ṣaka ni wọ́n kó gbogbo ẹrù wọn sí nígbà tí wọ́n lọ sí ìrìn àjò náà. Ìlà-Oòrùn Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí ni mo ti wá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n ò fẹ́ran ọmọ náà n ò rò pé ó lè pààyàn. Abẹ́rẹ́ mẹ́ta ni ó gbà sí apá rẹ̀. Èmi ni Alága Ẹgbẹ́ Kásowọ́pọ̀. Àmì ayò mẹ́rin sí òdo ni Manchester United fi na Chelsea ní àná. Eéwo mú mi lábẹ́ etí. Àwọn iwin inú igbó ti ń jíròrò. Bàbá Adémọ́lá ti fayé sílẹ̀ láti ìgbà tí a ti wà ní ilé ìwé gíga. Mo fẹ́ lọ gba atẹ́gùn ní’ta. Ọmọ yẹn ò lẹ́kọ̀ọ́. À ná tó ẹgbẹ̀rún náírà sí nǹkan ọ̀hún. Aláta rodo ti dé o, ṣé ẹ fẹ́ rà àbí ẹ ò rà? Ọ̀rọ̀ máa jáde lóru òní. Apá Káróunwí ti kán. Àwọn àgbò ń kan ara wọn pa. Ọkùnrin ni adarí ìjọ náà. Wọ́n máa ń lo orin dadakùádà lati fi ki oríkì ènìyàn. Àwọn ọ̀rẹ́ méjì ń ya àwòrán láàárọ̀ ọjọ́ náà. Akíntúndé ti ṣètò gbogbo ìwé ìrìn àjò mi. Àgùntàn l’ẹranko tó gọ̀ jù. Kí gbogbo ayé ó wá bá wa dá sí ọ̀rọ̀ yìí, kó tó pokúlúrúmuṣu. Ilẹ̀ náà kìí ṣe ilẹ̀ olómi, ẹ ó gbádùn rẹ̀. Wọ́n máa gun Àràfá ní ọ̀la. Kò sí bí èèyàn kan ṣe le kàwé tó, kò lè mọ gbogbo ǹkan tán nílé ayé. Àgbònrín mẹ́ta ń sọdá. Ọlárótìmí fẹ́ràn ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, ohun èlò tí ó fẹ́ràn láti máa lù nìyẹn. Crowdsourced high-quality Yoruba speech data set. Identifier: SLR86 Summary: Data set which contains recordings of Yoruba. Category: Speech License: Attribution-ShareAlike 4.0 International Downloads (use a mirror closer to you): about.html (Information about the data set. ) Mirrors: LICENSE (License information for the data set. ) Mirrors: line_index_female.tsv (All utterances for the female speakers. ) Mirrors: line_index_male.tsv (All utterances for the male speakers. ) Mirrors: yo_ng_female.zip (Archive file with all audio for the female speakers. ) Mirrors: yo_ng_male.zip (Archive file with all audio for the male speakers. ) Mirrors: annotation_info.txt (A file listing additional annotations in the text. ) Mirrors: About this resource: This data set contains transcribed high-quality audio of Yoruba sentences recorded by volunteers. The data set consists of wave files, and a TSV file (line_index.tsv). The file line_index.tsv contains a anonymized FileID and the transcription of audio in the file. The file annotation_info contains information annotations included in the data set. The data set has been manually quality checked, but there might still be errors. Please report any issues in the following issue tracker on GitHub. https://github.com/google/language-resources/issues See LICENSE file for license information. Copyright 2018, 2019, 2020 Google, Inc. If you use this data in publications, please cite it as follows: @inproceedings{gutkin-et-al-yoruba2020, title = {{Developing an Open-Source Corpus of Yoruba Speech}}, author = {Alexander Gutkin and I{\c{s}}{\i}n Demir{\c{s}}ahin and Oddur Kjartansson and Clara Rivera and K\d{\'o}lá Túb\d{\`o}sún}, booktitle = {Proceedings of Interspeech 2020}, pages = {404--408}, month = {October}, year = {2020}, address = {Shanghai, China}, publisher = {International Speech and Communication Association (ISCA)}, doi = {10.21437/Interspeech.2020-1096}, url = {http://dx.doi.org/10.21437/Interspeech.2020-1096}, } |