text
stringlengths
1
44.6M
Nínú ìpè kan lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n sọ fún aṣojú iléeṣẹ́ BlaBlaCar pé ètò náà ti yí padà, pé àwọn á máa ṣe ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ pẹ̀lú àwọn oníbàáràa wọn dípò wọn.
Nítorí kò sí nǹkan tí ọkùnrin ò lè ṣe láì nááni nígbà tí nǹkan tó tàsé bá ṣẹlẹ̀.
Bí i kó pariwo. Kí ó kígbe mọ́ ẹ?
Tí ó ń lé e lọ sọ́nà etí odò Akókurà, tí ó bẹ̀ẹ́ pé kí ó padà, tí ó ń bẹ́ẹ̀ kí ó tó di wí pé ó kọjá odò náà.
Èṣúńiyì mọ̀ iṣẹ́ rẹ̀ dunjú. Màmá tirí bí ó ṣe yanjú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ mẹ́ta ní abúlé .…
Làbákẹ́ wo ọkùnrin náà. Ojú rẹ̀ ti gán-án-ní nọ́mbà ọkọ̀ náà.
Ohun tí a kọ sí ojú pátákó: "Gbé Ìgbésẹ̀ kí o sì kọ àjọ̀dún Òyìnbó" àti "Ṣe ìgbélárugẹ àṣà ìbílẹ̀, kọ àjọ̀dún Òyìnbó".
Bákan náà ni Omarah gbóríyìn fún iléeṣẹ́ eré orí ìtàgé Nollywood ti Nàìjíríà.
Ìrò olóòtú ìwé ìròyìn Punch pe ìhùwàsíi Buhari gẹ́gẹ́ bíi ti apàṣẹ-wàá àti pé ìwà náà lè fa rògbòdìyàn-an ti òfin:
Àwọn elétò náà sọ pé ó "nírú ẹ̀yà" tí àwọn olugbọ́ àwọn ń fẹ́.
Òkúta inú òkun Buccoo Reef tí o gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ta tí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ máa ń wọ́ tùùrùtù níbẹ̀ náà kò gbẹ́yìn.
Ó tí mọ́ ọn lára.
Ara rẹ̀ yá gágá, inú rẹ̀ dùn láti ṣe alábàpàdé àwọn ọ̀rẹ́ tí ó wá láti ilẹ̀ẹ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló mọ̀ pé ó lé sọ èdè Tibet.
Bí ẹjá bá sì tán lómi, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn apẹja nìyẹn.
Ajà-fún-ẹ̀tọ́-ọmọnìyàn yìí ń jáde lábẹ́ àsíá African Action Congress.
Làbákẹ́ pa ilẹ̀kụ̀n ìyẹ̀wù náà dé jẹ́jẹ́ lèyín rẹ̀, ẹ̀rín músẹ́ tó múnúdùn ni ọ̀rẹ́ rẹ̀, olùgbàlejò ìyèwù náà fi pàdé rẹ̀.
Lọ́jọ́ 15 oṣù Ọ̀wàrà, akọ̀ròyin Guinea Bhiye Bary kọ:
Ọgbà oníṣègùn náà wà níbí i máìĺì márùn-ún sí Abúlé Àgé, tí a dátẹ̀ sínú igbó kìjikìji. Ọgbà náà fẹjú, ó sì wá lórí sarè ilẹ̀ mẹ́rin tí á fi ògiri gíga tí wọn fi sìmẹ́ǹtì rẹ́ yípo rẹ̀, tí wọ́n sì to ìgò àfọ́kù àti wáyà fẹ́léfẹ́lẹ́ sí i.
Ọpọ́n èdè Yorùbá yóò sún síwájú bí àwọn tó ń fọ èdè náà bá lọ́wọ́ sí ìdàgbàsókè rẹ̀; ìlò rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn pọn dandan ní ìbámu pẹ̀lú bí ayé ṣe ń lu jára wọn bí ajere lóde òní.
Kolibri jẹ́ iṣẹ́ àìrídìmú tí a lè ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ si orí ọ̀pọ̀ ohun èlò ẹ̀rọ-ayárabíàṣá láì nílò ìṣàsopọ̀ ẹ̀rọ-ayélujára.
Ìfòfinlíle mú àtakò
À ń já ìbàǹtẹ́ ẹ̀ lẹ́yìn, ó ń já tará iwájú.
Ọjọ́ yìí, tún jẹ́ àyájọ́ ọjọ́ tí orílẹ̀-èdè Mauritania gba òmìnira lọ́wọ́ France ní ọdún 1960, lé góńgó sọ́kàn àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Mauritania kan tí wọ́n ń wá ìdájọ́ òdodo fún ìpakúpa tí wọ́n pa àwọn ọkùnrin 28 yìí, tí gbogbo wọn sì jẹ́ aláwọ̀ dúdú.
Ẹni à bá tà ká fowóo rẹ̀ ra èbù: ó ní èlé òún kó ọ̀ọ́dúnrún.
Dídọ̀gba abo atakọ
Màmá! Ó wọ inú ilé – tí Èṣùníyì sì tẹ̀lé e.
Kódà ní orílẹ̀-èdè yìí níbi tí a wà báyìí, òótọ́ ni.
Àì-lápá làdá ò mú; bí a bá lápá, ọmọ owú too gégi.
Bí iye àwọn tí ó ti kó àrùn yìí ṣe ń pọ̀ káàkiri Orílẹ̀-èdè China, àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera ti wà digbí, tí wọ́n sì tún kóná mọ́ ètò ìlera tí kò sùwábọ̀ tó fún ìtọ́jú àwọn ọ̀kẹ́ àìmọye arúgbó tó kún ìlú.
Ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń ṣètọ́ jú àwọn alárùn ọpọlọ kán wà ní òpin ìlú - ní ìdojúkọ ìlà-oòrùn - ilé ọlọ́dà funfun lórí òkè.
Ohun tí Keyamo fẹ́ ṣe ni láti fi hàn wípé ìṣàkóso ìjọba Buhari ti gbé ìgbésẹ̀ àtúnṣe sí àwọn ọ̀nà ọkọ̀ọ ojú irin tí ìjọba àná pa tì.
Ẹ wòye ara yín, tí o bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, o jẹ́ ọ̀dọ́bìnrin nílẹ̀ Adúláwọ̀, ò ń lọ sí ilé-ìwòsàn tàbí ààyè-ìtọ́jú.
Àwọn ènìyàn ń f’ẹ̀sùn kan àwọn ẹlẹyẹ fún iṣẹ́-ibi ọwọ́ọ wọn: ikú ènìyàn tàbí ẹranko, ọ̀dá òjò, àìso jìngbìnnì irúgbìn, àti bẹ́èbẹ́è lọ.
Ní gbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó dé ọ̀dọ̀ àwọn awakọ̀ ọkọ̀ akẹ́rù náà.
Á kọ́ bí yóò ti ṣe mọ rírì ọ̀rọ̀ mi nísinsìnyí tí ó ti ń kó sí páńpẹ́ rẹ̀.
Ìgbàkigbà tí wọ́n bá pàdé, ọ̀rọ̀ wọn máa ń dà bíi òwe “Àáyáà ti Ògúngbè”, ọdẹ ni Ògúngbè, ó gẹ̀gùn sílẹ̀ de àáyá.
Lọ́jọ́ kejì, nígbà tí ó lajú sáyé, ó bẹ̀rẹ̀ síí gbẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ọ rẹ̀ nìkan láì lo ìtúlẹ̀.
Ó wo ìyá rẹ̀ díẹ̀, ó sì tún yíjú sí tábìlì ibi tí oúnjẹ wà ó jọ wí pé kò ì tí ì pinnu èyí tó fẹ́ ṣe…. Kò sí ìdí fún un láti kánjú ní ti Màmá.
Ajá rí epo kò lá; ìyáa rẹ̀ẹ́ ṣu ihá bí?
Báwo ni yóò ṣe ṣe é ṣe, láti máa fi gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pamọ́ fún Làbákẹ́?
Ó jọ àsìkò tí ó yẹ láti bá Àlàmú sọ̀rọ̀. Láti bi í ní àwọn ìbéèrè díẹ̀, àsìkò tí ó dára jù láti fún un ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ abẹ́lé tó péye.
Àfàìmọ̀ kí Àlàmú má fi ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí ó kàn kúrò níwájú rẹ̀, tàbí kí ó tilẹ̀ ki eré mọ́lẹ̀.
“Bẹ́ẹ̀ni. Ọbẹ̀ ni Màmá… Ọbẹ̀ tó dára. Kí ló kù?”,
Ṣùgbọ́n nísinyìí a ní àwọn ànfàní láti gberawa lẹ́yìn ní àwọn ọ̀nà tí a kò lè ṣe tẹ́lẹ̀.
Ṣàyẹ̀wò bóyá o ṣàtẹ̀wọlé àmì bí ó ṣe tọ́
Ó tún bẹ̀rẹ̀ ẹ̀rín tí ó máa ń rín yẹn, sí ara rẹ̀, gbohùn-gbohùn ilé sì ń gba ohùn rẹ̀, ariwo rẹ̀ yìí sì ń da àwọn aládùúgbò wọn láàmú.
Sùgbọ́n yóò padà nípa ọ̀tọ̀ lára mi.
Ṣàfikún tí ó bágbà mu sórí Kolibri láti rí àwọn ohun àmúlò
Àwọn tí ó ṣì ń dúró ti di ẹgẹrẹmìtì, èyí á mú kí àwọn kan ó máa lọ (ṣe ayédèrú ìwé láti) gbẹ́sẹ̀ lé ilé wọ̀nyí.
Òpin okùn náàrè é! Ṣè bí wọ́n máa ń sọ pé okùn ìfẹ́ tó so ọkọ àti ìyàwó pọ̀ yió sì le?
Ìgbìyànjú láti so pọ̀ mọ́ apèsè…
Bẹ́ẹ̀ ni, Làbákẹ́ láti fi lé ìbànújẹ́ kúrò.
Ó gbé nǹkan àjèjì náà sí orí àga ìgbénǹkanlé, ó sì tan ẹ̀rọ àmóhùnmáwòrán, kàyéfì ló jẹ́ fún un, ohun tí ó gbé sórí àga di àwátì.
Ìkànnì tí kò sí lákàálẹ̀
Ní ìṣẹ́ju àáyá kan, àwòrán alága àwọn ẹgbẹ́ awakọ̀ wá sí ọkàn Làbákẹ́ – ó lára, ó níkùn agbè, ó ń rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì ń juwọ́ tayọ̀ tayọ̀ sí awakọ̀ ọkọ̀-akẹ́rù náà.
Fún àpẹẹrẹ, wọ́n gbẹ́ kòtò sínú iyẹ̀pẹ̀, wọ́n sì rì wá mọ́lẹ̀ dé ibi ọrùn, orí wa ò ṣe é yí, ojú wa sì wà ní ìhà oòrùn.
Gbogbo bí Làbákẹ́ ṣe ń siṣẹ́ ilé, màmá ń fi ìwò ìyọnu lé e ká, wọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀, wọ balùwẹ̀, wọ ilé ìdáná, àti parí parí ẹ̀, lọ sínú yàrá rẹ̀, níbi tí wíwò màmá dè é mọ́!
Lo àtẹìjúwe àjúmọ̀ṣe náà láti túmọ̀ ìparadà tí ó tọ́
Onímọ̀ nípa àjọṣepọ̀ ènìyàn láwùjọ ni mí, mo dẹ̀ tún jẹ ìyá àwọn ọmọdébìnrin méjì.
Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tí ó bá lóyún kì í padà sí ilé ìwé pàápàá tí ó bá bímọ tán.
Bákannáà ni ó rí fún orin wa àti ohun tí ó rọ̀ mọ́, Ska, Mento, Rock Steady, Reggae àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọmọ bíbíi Zanzibar, tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ọ DCMA nígbà kan rí, tí ó jẹ́ olùkọ́ni ní iléèwé kan náà báyìí, Amina Omar Juma tòun ti ìlú mọ̀ọ́ká ẹgbẹ́ akọrin rẹ̀, tí ó ń "fi àṣà ìró orin ìbílẹ̀ " taarab papọ̀ mọ́ ti ìgbàlódélonígbàńlò kọrin, ìyẹn "Siti àti Ẹgbẹ́ ", ṣẹ̀ṣẹ̀ padà wọ̀lú láti ìrìnàjò orin kíkọ kan ní orílẹ̀-èdèe South Africa.
Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, Ààrẹ àná orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ó fún imú rẹ̀, omi jáde lójú rẹ̀, etí rẹ̀ di fún ìsẹ́jú kan.
Ó jẹ ṣónṣó ayọ̀ rẹ̀, irú ìgbà ayọ̀ bẹ́ẹ̀ ò padà dè bá Màmá mọ́. Ilé ayé jẹ́ ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ìyà gígùn kan. Tí kò lópin.
Ó fi ipá gba agbára lọ́wọ́ NJC tí ó ní àṣẹ ní abẹ́ òfin láti sọ bóyá kí a rọ adájọ́ tàbí aṣojú-ṣòfin (ilé ìgbìmọ̀ àgbà) ní oyè, tí yóò sì fi ohùn sí irúfẹ́ ìgbésẹ̀ náà.
Ọ̀kan nínú àwọn ìbéèrè abẹ́ rẹ̀ tọ́ka sí “Fırtınadayım, (mo wà nínú ìjì), orin olórin tàka-n-súfèé kan Mabel Matiz tí í ṣe LGBTQ “Fırtınadayım” (“I am in the storm”):
Akọ̀wé ìṣirò owó ti pe Àlàmú , ó sì na wọ́ ìwé pélébé tí ó kọ owó tí ó ṣẹ́kù fún un sí.
Ní Cape Verde, agbègbè erékùṣù tí ó ní èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún 560, tí idà 57 wọn ń lo ẹ̀rọ-ayélujára, ìyẹn gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí Ilé Ìfowópamọ́ Àgbáyé ṣe ní ọdún 2017 ti ṣe fi hàn.
Ẹ̀yin obìnrin léwu gan an. Gbogbo yín lẹ dùn ún rí tẹ́ ẹ rẹwà. ṣùgbọ́n àti súnmọ́ ọn yín, iná ni o... 'Iná?'
Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti jẹ gàba lórí ìbánisọ̀rọ̀ tí ó ń wáyé ní orí ẹ̀rọ ayélukára-bí-ajere gẹ́gẹ́ bí èdè "gbogbo àgbáyé" fún ìtàkùrọ̀sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ẹ̀rọ ayélujára.
Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó sùn.
Adìyẹ́ tó ṣu tí kò tọ̀, araa rẹ̀ ló kù sí.
Láti mú kí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ àti ọmọ àgbáyé ó fi ọkàn sí ìdájọ́ àti fún ìdásílẹ̀ẹ Alaa ní ọjọ́ 17 oṣù Ẹrẹ́nà.
Mo lérò wí pé ẹ máa kórìra mi ni.
Ìdámọ̀ràn ohun tí ó lè fa sábàbí àrùn náà kan fi yé wí pé kòkòrò àìfojúrí kòrónà jẹ yọ látàrí ẹran ejò tàbí ẹran àdán tí àwọn ará China máa ń jẹ l'óúnjẹ, tí wọ́n ń tà ní ọjà Huanan wet ní agbègbè Wuhan níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní èrò wí pé ibẹ̀ ni orísun kòkòrò àìfojúrí yìí.
Oníbàárà mi, ọ̀gbẹ́ni Àlàmú Ọláoyè ti jìyà àìmọ̀dí àti ìtìjú látàri irọ́ àìlèṣe ojúṣe-ẹni àti ìṣowó-kúmo-kùmo tí wọ́n pa mọ́ ọn, tí wọ́n sì fún un níwèé ìyọníṣẹ́ tí alábòójútó òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ Bajoks fún un.
Ẹ wá wọ àdúgbò náà lọ, ẹ wá ń bèrè, "kí ló ń ṣẹlẹ̀ níbí? " ní àkọ́kọ́ àwọn ẹnìyan lọ́ra láti sọ fún yín.
Làbákẹ́ ni ìyàwó kan ṣoṣo fún ọmọ kan ṣoṣo tí màmá ni….
Ẹ wò ó bí ó ṣé ń wò, tàfojúdi tàfojúdi. Ẹ wò bí óṣe ń ṣu ẹnu pọ̀. Ẹ wo iná lójú rẹ̀ kékeré.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ṣe kókó fún àjọ ọlọ́pàá àti oníṣègùn nítorí àwọn ni kì í mú ayé rọrùn fún Abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn tí ó bá ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ tàbí nílò ìrànlọ́wọ́ ètò ìlera.
Ìgbà àkọ́kọ́ tí mo rí ẹranko igbó ní orílẹ̀-èdè mi nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, bó tilẹ̀ jẹ́ wí pé kìnìhún àti àwọn ajá igbó ilẹ̀ Adúláwọ̀ ń gbé ní ibùsọ̀ díẹ̀ sí ilé mi.
Èyí ni a pè ní ìsẹ́ ẹ̀rọ-ayélujára tàbí ìdígàgá, tí í ṣe irúfẹ́ ìtẹríbọlẹ̀ kan.
Màmá ní ìpinnu líle kan lọ́kàn rẹ̀ pé nígbà tí ó bá tún fojú kan Làbákẹ́, ìtàn náà á yàtọ̀.
Bí òǹkà àwọn tí wọ́n ti ní kòkòrò yìí ṣe ń lọ sókè sí i lójoojúmó, àáríngbùngbùn Orílẹ̀-èdè China tí i ṣe Hubei àti Olú-ìlú rẹ̀ tí í ṣe Wuhan ti ní ìdojúkọ tó gogò lórí ètò ìlera, tí àpapọ̀ àwọn tí wọ́n ń gbé lágbègbè yìí sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ́rùn ní ìlọ́po 60.
Bí àwọn ènìyàn ìlú kan bá mú àjọyọ̀ àjọ̀dún ìlú mìíràn ní òkúnkúndùn ju bí ó ṣe yẹ, èyí fi hàn wípé orílẹ̀-èdè náà ń jẹ ìyà ìgbógunti àṣà.
Kì í ṣe COVID-19 nìkan ni famínfà tí ó yí Ìdánowò YKS ká ní ọdún 2020.
Àwa ní olú ilé iṣẹ́ẹ SEBIN headquarters àti pé wọ́n ní àwọn kò ní í [ní àhámọ́ àwọn] #NiboNiLuisCarlosWa.
“Bẹ́ẹ̀ ni…ah? Èwo níbẹ̀?”
Ní àgbáyé, ọmọ-ìlú ní ẹ̀tọ́ láti wá àìṣedéédé aláṣẹ ìjọba.
Ó lè má fọkàn sí o.
OníṢàngó tó jó tí kò gbọn yẹ̀rì: àbùkùu Ṣàngó kọ́; àbùkù ara ẹ̀ ni.
Ìjọba Burundi ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìkanra mú ìwà àtakò láti ọdún 2015, lẹ́yìn ìjákulẹ̀ ìṣọ̀tẹ̀ kan, ìdojúkọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ adìtẹ̀ kan, àtakò lórí ìlòkulò ẹ̀tọ́, òfin kànńpá, ìnira pẹ̀lú ètò ọrọ̀-ajé àti rògbòdìyàn àwọn asásàálà.
Àwòrán láti ọwọ́ọ Ọmọ Yoòbá, tí a gba àṣẹ láti lò.
Bí ènìyàn bá tọ̀ mí wá fún ìrànlọ́wọ́, mo máa dúró tì wọ́n gbágbágbá, ó sọ nínúu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò orí ẹ̀ro-ìbánisọ̀rọ̀ kan.
Ìṣàsopọ̀ Àìrí Ìkọ̀kọ̀ (VPN) máa ń yí dátà padà sí odù ààbò, yóò sì fi gbogbo dátà ránṣẹ́ láti orí ẹ̀rọ-ayélujáraà rẹ sóríi ẹ̀rọ ayárabíàṣá mìíràn.
Ojú-ìwé Facebook ti BBC Bangla rọ àwọn òǹkàwée rẹ̀ láti jábọ̀ àwọn ìgbésẹ̀ akin tí àwọn òníṣẹ́ ìlú Dhaka ń gbé láti gbógun ti ẹ̀fọn.
Láti ayée àmòdi sí ayé irú àwọn "àjàkálẹ̀-àrùn báwọ̀n-ọnnì", àwọn aṣojú ìjọba ìfipámúnisìn sábà máa ń fi àwọn Ọmọ Adúláwọ̀ ṣe ohun èlò fún ìdánwò láì gba àṣẹ, Malloy kọ pé "...ẹ̀jẹ̀ Ọmọ Adúláwọ̀ ni ó dára jù lọ láti fi bọ́ iṣẹ́ ìwádìí egbògi ayé ìjọba amúnisìn".
Wọ́n pe ìpolongo wọn ní "Ẹ Yé é Dà Wá", wọ́n gbà pé ìwà ọ̀dàlẹ̀ jẹ́ ìdí tí ó tọ́ láti máa fìyà jẹ obìnrin.
Nǹkan tí ó ń sọ fún Èṣùníyì pé kí ó ṣe nìyẹn tí ariwo àwọn wèrè yẹn fi tún pọ̀ sí i.