Ẹ̀KỌ́ ÀTI ÀWỌN MÁJẸ̀MÚ TI ÌJỌ JÉSÙ KRÍSTÌ TI ÀWỌN ÈNÌYÀN MÍMỌ́ ỌJỌ́-ÌKẸ̀HÌN TÍ Ó NÍ ÀWỌN ÌFIHÀN TÍ A FIFÚN JOSEPH SMITH, WÒLÍÌ NÁÀ PẸ̀LÚ ÀWỌN ÀFIKÚN LÁTI ỌWỌ́ ÀWỌN ÀTẸ̀LÉ RẸ̀ NÍNÚ ÀJỌ ÀÀRẸ TI ÌJỌ NÁÀ A tẹ̀ ẹ́ láti ọwọ́ Íjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn ìlú-nlá Salt Lake, Utah, ilẹ̀ Amẹ́ríkà Ọ̀RỌ̀ ÌṢAÁJÚ Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ni àkójọpọ̀ àwọn ìfihàn àtọ̀runwá àti àwọn ìkéde tí ó ní ìmísí ti a fúnni fún ìdásílẹ̀ àti ìlànà ti ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ púpọ̀ nínú àwọn ìpín náà jẹ́ àwọn tí a darí wọn sí àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn mímọ́ Ọjọ́-ìkẹ̀hìn, àwọn ọ̀rọ̀ ìfiránṣẹ́, àwọn ìkìlọ̀, àti àwọn ìyànjú tí ó wà fún ire gbogbo aráyé ó sì jẹ́ ìpè sí gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti gbọ́ ohùn Olúwa Jésù Krístì, tí ó nsọ̀rọ̀ sí wọn fún wíwà ní àlàáfíà ti ara àti ìgbàlà ayérayé wọn. Púpọ̀jùlọ nínú àwọn ìfihàn náà nínú ìkójọpọ̀ yìí ni a gbà nípasẹ̀ Joseph Smith Kékeré, tí ó jẹ́ wòlíì àkọ́kọ́ àti ààrẹ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Àwọn míràn jẹ́ èyí tí ó jade nípasẹ̀ díẹ̀ nínú àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ nínú Àjọ Ààrẹ (wo àwọn àkọlé sí Ẹ&M 135, 136, àti 138, àti àwọn Ìkéde Lábẹ́ Àṣẹ 1 àti 2). Ìwé Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn idíwọ̀n iṣẹ́ Ìjọ ní àpapọ̀ pẹ̀lú Bíbélì Mímọ́, Ìwé ti Mọ́mọ́nì, àti Péálì Olówó Iyebíye. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nítorítí kìí ṣe ìtumọ̀ àwọn ìwé àtijọ́, ṣùgbọ́n orírun rẹ̀ jẹ́ ti òde òní a sì fifúnni láti ọwọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn àsàyàn wòlíì Rẹ̀ fún ìmúpadàbọ̀-sípò iṣẹ́ mímọ́ Rẹ̀ àti ìgbékalẹ̀ ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyìí. Nínú àwọn ìfihàn náà, a ngbọ́ ohùn jẹ́jẹ́ ṣùgbọ́n dídúró ṣinṣin ti Olúwa Jésù Krístì, tí ó nsọ̀rọ̀ lákọ̀tun ní ìgbà kíkún ti àwọn àkókò; àti iṣẹ́ tí a ti bẹ̀rẹ̀ níhĩnyí jẹ́ ìmúrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Rẹ̀ Ẹ̀kejì, ní ìmúṣẹ àti ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ti gbogbo àwọn wòlíì mímọ́ láti ìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀. Joseph Smith Kékeré ni a bí ní 23 Oṣù Kejìlá, 1805, ní Sharon, Agbègbè Windsor, Vermont. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé rẹ̀, ó ṣípòpadà pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ lọ sí Manchester ọjọ́ òní, ní ìwọ̀ oòrùn New York. Ó jẹ́ pé ìgbàtí ó ngbé níbẹ̀ ní ìgbà ìrúwé 1820, nígbàtí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlá ní ọjọ́ orí, ni ó ní ìrírí ìran rẹ̀ àkọ́kọ́, nínú èyítí Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, àti Ọmọ Rẹ̀ Jésù Krístì bẹ̀ẹ́ wò fúnra wọn. A sọ fún un nínú ìran yìí pé Ìjọ òtítọ́ ti Jésù Krístì tí a ti gbékalẹ̀ ní àwọn ìgbà Májẹ̀mú Titun, àti tí ó ti ṣe àbójútó ẹ̀kúnrẹrẹ́ ìhìnrere náà, kò sí lórí ilẹ̀ ayé mọ́. Àwọn ìṣípayá àtọ̀runwá míràn tẹ̀lé e nínú èyítí a ti kọ́ ọ láti ọwọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ángẹ́lì; a fi hàn sí i pé Ọlọ́run ní iṣẹ́ pàtàkì fún un láti ṣe lórí ilẹ̀ ayé àti pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ó mú Ìjọ Jésù Krístì padàbọ̀ sípò sí orí ilẹ̀ ayé. Bí àkókò ṣe nlọ, Joseph Smith ni a mú kí ó ṣeéṣe fún nípasẹ̀ ìranlọ́wọ́ àtọ̀runwá láti túmọ̀ àti láti ṣe àtẹ̀jáde Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní àkókò yìí kannáà òun àti Olíver Cowdery ni a yàn sí Oyè-àlùfáà ti Áarónì láti ọwọ́ Jòhánnù Onítẹ̀bọmi nínú Oṣù Karũn 1829 (wo Ẹ&M 13), àti ní kété lẹ́hìnnáà a yàn wọ́n sí Oyè-àlùfáà ti Melkisédekì láti ọwọ́ àwọn Àpóstélì ìgbàanì Petérù, Jamesì, àti Jòhánnù (wo Ẹ&M 27:12). Àwọn jíjẹ-oyè-àlùfáà mĩràn tẹ̀lé e nínú èyítí àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà ti di fífúnni láti ọwọ́ Mósè, Èlíjà, Élíásì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlíì ìgbàanì (wo Ẹ&M 110; 128:18, 21). Àwọn jíjẹ-oyè-àlùfáà wọ̀nyìí jẹ́, ni tòótọ́, ìmúpadàbọ̀-sípò àṣẹ àtọ̀runwá fún ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. Ní 6 Oṣù Kẹrin 1830, lábẹ ìdarí láti ọ̀run wá, Wòlíì Joseph Smith ṣe ètò Ìjọ náà, báyìí sì ni Ìjọ òtítọ́ Jésù Krístì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan síi bíi àgbékalẹ̀ kan láàrin àwọn ènìyàn, pẹ̀lú àṣẹ láti kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìhìnrere àti láti ṣe àbójútó àwọn ìlànà ìgbàlà. (Wo Ẹ&M 20 àti Péálì Olówó Iyebíye, Joseph Smith—History 1.) Àwọn ìfihàn mímọ́ wọ̀nyí ni a gbà ní ìdáhùn sí àdúrà, ní àwọn àkókò àìní, wọ́n sì jade wá láti inú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tòótọ́ ní ìgbé ayé àwọn ènìyàn gidi. Wòlíì náà àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ wá ìtọ́ni àtọ̀runwá, àwọn ìfihàn wọ̀nyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n rí i gbà. Nínú àwọn ìfihàn náà a nrí ìmúpadàbọ̀-sípò àti ìfarahàn ìhìnrere Jésù Krístì àti gbígbà wọlé ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò. Ṣíṣípòpadà Ìjọ lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn láti New York àti Pennsylvania sí Ohio, sí Missouri, sí Illinois, àti ní ìkẹ̀hìn sí Great Basin ti ìwọ̀ oòrùn Amẹ́ríkà àti àwọn ìgbìyànjú tí ó ní agbára ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní gbígbìdánwò láti kọ́ Síónì sí orí ilẹ̀ ayé ní àwọn àkókò òde òní ni a fi hàn bákannáà nínú àwọn ìfihàn wọ̀nyí. Púpọ̀ nínú àwọn ìpín ìbẹ́rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ nípa ìyírọ̀padà àti ṣíṣe àtẹ̀jade Ìwé ti Mọ́mọ́nì (wo àwọn ìpín 3, 5, 10, 17, àti 19). Àwọn ìpín díẹ̀ lẹ́hìnnáà ṣe àfihàn iṣẹ́ Wòlíì Joseph Smith ní síṣe ìyírọ̀padà Bíbélì pẹ̀lú ìmísí, láàrin ìgbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpín pàtàkì ti ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ jẹ́ gbígbà (wò, fún àpẹrẹ, àwọn ìpín 37, 45, 73, 76, 77, 86, 91, àti 132, ọ̀kọ̀ọ̀kan èyítí ó ní ìbáṣepọ̀ tààrà pẹ̀lú ìyírọ̀padà Bíbélì). Nínú àwọn ìfihàn náà, àwọn ẹ̀kọ́ ìhìnrere ni a gbé kalẹ̀ pẹ̀lú àwọn àlàyé nípa irú àwọn ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ bí ìwà ọ̀run ti Ọlọ́run Olórí, orírun ènìyàn, jíjẹ́ òdodo Sátánì, èrèdí ara ikú, ṣíṣe dandan ìgbọ́ràn, ìdí fún ironúpìwàdà, àwọn iṣẹ́ ṣíṣe ti Ẹ̀mí Mímọ́, àwọn ìlànà àti ìṣesí tí wọ́n jẹ mọ́ ìgbàlà, àyànmọ́ ilẹ̀ ayé, àwọn ipò ènìyàn ní ọjọ́ iwájú lẹ́hìn Àjínde àti Ìdájọ́, jíjẹ́ ayérayé ìbáṣepọ̀ ìgbéyàwó, àti àdánída jíjẹ́ ayérayé ti ẹbí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ìfarahàn díẹ̀díẹ̀ ti ètò iṣẹ́ àbójútó Ìjọ ni a fihàn pẹ̀lú pípè àwọn bíṣọ́pù, Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Ìgbìmọ̀ ti àwọn Méjìlá, àti ti Àádọ́rin àti ìgbékalẹ̀ àwọn ipò iṣẹ́ ìdarí àti àwọn ìyejú mĩràn. Lákotan, ẹ̀rí tí a fifúnni nípa Jésù Krístì—ìwà ọ̀run Rẹ̀, ọlá nlá Rẹ̀, pípé Rẹ̀, ìfẹ́ Rẹ̀, àti agbára ìrànipadà Rẹ̀—mú kí ìwé yìí níye lórí púpọ̀ sí ìran ènìyàn ó sì “níye lórí sí Ìjọ bíi àwọn ọrọ̀ ti gbogbo Ilẹ̀ Ayé” (wo àkọlé sí Ẹ&M 70). Àwọn ìfihàn náà jẹ kíkọsílẹ̀ ní ojúlówó láti ọwọ́ àwọn akọ̀wé Joseph Smith, àwọn ọmọ Ìjọ sì fi tọkàntọkàn pín àwọn ẹ̀dà àfọwọ́kọ pẹ̀lú ara wọn. Láti ṣe ẹ̀dá àkọsílẹ̀ tí yío pẹ́ títí síi, láìpẹ́ àwọn àkọ̀wé ṣe ẹ̀dà àwọn ìfihàn wọ̀nyí sí inú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ àfọwọ́kọ, èyítí àwọn olùdarí Ìjọ lò ní ṣíṣe ìpalẹ̀mọ́ àwọn ìfihàn náà lati jẹ́ títẹ̀. Joseph Smith àti àwọn Ènìyàn Mímọ́ ìbẹ́rẹ̀ wo àwọn ìfihàn náà bí wọ́n ṣe wo Ìjọ: ní jíjẹ́ alààyè, níní ipá, tí ó sì le jẹ́ títúnṣe pẹ̀lú àfikún ìfihàn. Bákannáà wọ́n dáamọ̀ pé ó ṣeéṣe kí àwọn àṣìṣe àìtinúwá ti ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ ìgbésẹ̀ ti ṣíṣe ẹ̀dà àwọn ìfihàn náà ati ṣíṣe ìpalẹ̀mọ́ wọn fún títẹ̀jáde. Nípa báyìí, ìpàdé àpapọ̀ kan ti Ijọ́ pe Joseph Smith ní 1831 láti “ṣe àtúnṣe àwọn àṣìṣe tàbí àìdára èyítí òun le ti ṣe àwárí nípa Ẹ̀mí Mímọ́.” Lẹ́hìn tí àwọn ìfihàn náà ti di gbígbéyẹ̀wò ati títúnṣe, àwọn ọmọ Ìjọ ní Missouri bẹ̀rẹ̀ sí títẹ ìwé kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Ìwé Àwọn Òfin fún ìṣèjọba ti Ìjọ Krístì, èyítí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfihàn ìbẹ̀rẹ̀ ti Wòlíì nínú. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìgbìdánwò àkọ́kọ́ yìí láti tẹ̀ àwọn ìfihàn náà parí, nígbàtí àwọn jàndùkú èrò kan ba ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ jẹ́ ní Jackson County ní 20 Oṣù Keje, 1833. Ní gbígbọ́ nípa ìparun ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé ti Missouri, Joseph Smith àti àwọn olùdarí Ìjọ mìíràn bẹ̀rẹ̀ àwọn ìpalẹ̀mọ́ láti tẹ àwọn ìfihàn náà ní Kirtland, Ohio. Lẹ́ẹ̀kansíi láti ṣe àtúnṣe àwọn àṣìṣe, ṣe àfọ̀mọ́ àwọn ọ̀rọ̀, àti ṣe ìdámọ̀ àwọn ìdàgbàsókè nínú ẹ̀kọ́ àti ìgbékalẹ̀ Ìjọ, Joseph Smith mójútó yíyẹ̀wò ọ̀rọ̀ inú àwọn ìfihàn kan láti palẹ̀ wọn mọ́ fún títẹ̀jáde ní 1835 bíi Doctrine and Covenants of the Church of the Latter Day Saints. (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ti Ìjọ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn). Joseph Smith fi àṣẹ sí àtúntẹ̀ míràn ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, èyítí ó jẹ́ títẹ̀jáde ní oṣù díẹ̀ péré lẹhìn ikú ajẹ́rìíkú ti Wòlíì ní 1844. Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ti ìbẹ̀rẹ̀ mọ rírì àwọn ìfihàn náà wọ́n sì rí wọn bíi àwọn ọ̀rọ̀ àfiránṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ní àkókò kan nígbàtí 1831 nparí lọ, onírúurú àwọn alàgbà Ìjọ fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ jẹ́rìí pé Olúwa ti jẹ́ ẹ̀rí sí ọkàn wọn nípa òtítọ́ àwọn ìfihàn náà. Ẹ̀rí yìí ni a tẹ̀ jáde nínú àtúntẹ̀ ti 1835 ti Ẹ̀kọ́ ati àwọn Májẹ̀mú bíi ẹ̀rí kíkọ ti àwọn Àpóstélì Méjìlá: Ẹ̀RÍ NÁÀ TI ÀWỌN ÀPÓSTÉLÌ MÉJÌLÁ SÍ ÒTÍTỌ́ TI ÌWÉ Ẹ̀KỌ́ ÀTI ÀWỌN MÁJẸ̀MÚ Ẹ̀rí náà ti àwọn Ẹlérìí sí Ìwé àwọn Òfin Olúwa, èyítí Ó fifún Ìjọ Rẹ̀ nípasẹ̀ Joseph Smith Kékeré, ẹnití a yàn nípasẹ̀ ohùn Ìjọ fún èrò yìí: Àwa, nítorínáà, ní ìfẹ́ láti jẹ́rìí sí gbogbo aráyé, sí olúkúlùkù èdá lórí ilẹ̀ ayé, pé Olúwa ti jẹ́rìí sí ọkàn wa, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a tú sí orí wa, pé àwọn òfin wọ̀nyí jẹ́ fífi fúnni nípa ìmísí Ọlọ́run, àti tí ó ní èrè fún gbogbo ènìyàn wọ́n sì jẹ́ òtítọ́ gan an. Awa fi ẹ̀rí yìí fún ayé, pẹ̀lú Olúwa bíi olùrànlọ́wọ́ wa; ó sì jẹ́ pé nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Bàbá, àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ni a fún wa ní ààyè láti ní ànfàní ti jíjẹ́rìí yìí sí ayé, nínú èyítí awa yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ní gbigbàdúrà sí Olúwa nígbà gbogbo pé kí àwọn ọmọ ènìyàn ó lè jẹ ànfàní nípa rẹ̀. Orúkọ àwọn Méjìlá náà ni: Thomas B. Marsh David W. Patten Brigham Young Heber C. Kimball Orson Hyde William. E. McLellin Parley P. Pratt Luke S. Johnson William Smith Orson Pratt John F. Boynton Lyman E. Johnson Nínú àwọn àtúntẹ̀ tẹ̀lé-n-tẹ̀lé lẹ́hìnwá ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, àwọn àfikún ìfihàn tàbí àwọn ohun àkọsílẹ̀ míràn ni a ti fi kún un, bí a ṣe gbà wọ́n àti bí a ṣe tẹ́wọ́gbà wọ́n nipa àwọn ìpéjọpọ̀ tàbí àwọn ìpàdé àpéjọpọ̀ ti Ìjọ tí ó ní àṣẹ. Àtúntẹ̀ ti 1876, tí a pèsè lati ọwọ́ Àlàgbà Orson Pratt ní abẹ́ ìdarí Brigham Young, ṣe ètò àwọn ìfihàn náà ní ìbámu sí àkójọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ ó sì mú àwọn àkọlé titun wá pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìṣaájú onítàn. Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àtẹ̀jáde ti Ọdún 1835, àwọn ẹ̀kọ́ méje tẹ̀lé-n-tẹ̀lé nípa ìmọ̀ ẹ̀sìn wà nínú rẹ̀ bákannáà; ìwọ̀nyí ni a fún ní àkòrí Lectures on Faith (Ìdánilẹ́kọ̃ lórí Ìgbàgbọ́). Ìwọ̀nyí ni a ti pèsè fún lílò ní Ilé Ẹ̀kọ́ àwọn Wòlíì ní Kirtland, Ohio, láti 1834 sí 1835. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ ànfàní fún ẹ̀kọ́ àti ìtọ́sọ́nà, àwọn ìdánilẹ́kọ̃ wọ̀nyí ni a ti yọ kúrò nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú láti àtẹ̀jáde 1921 nítorí ti a kò fi wọ́n fúnni tàbí gbé wọn kalẹ̀ bíi àwọn ìfihàn sí gbogbo Ìjọ. Nínú àtúntẹ̀ Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ti 1981 ní Èdè Òyìnbó, àwọn àwẹ́ ìwé mẹ́ta jẹ́ fífikún fún ìgbà àkọ́kọ́. Ìwọ̀nyí ni àwọn ìpín 137 àti 138, tí ó gbé àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ìgbàlà fún àwọn òkú kalẹ̀; àti Ìkéde Lábẹ́ Àṣẹ 2, ní kíkéde pé gbogbo ọkùnrin ọmọ Ìjọ tí wọ́n bá yẹ le jẹ́ yíyàn sí oyè àlùfáà láì ka ẹ̀yà tàbí àwọ̀ ara sí. Olukúlùkù àtúntẹ̀ titun ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ní àwọn àṣìṣe àtẹ̀hìnwá tí a ti túnṣe àti àfikún àwọn ọ̀rọ̀ ìwífúnni titun, pàápàá nínú àwọn abala onítàn ti àwọn àkọlé ìpín. Àtúntẹ̀ ti lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí tún àwọn ònkà ọjọ́ ṣe síi àti àwọn orúkọ ibìkan ó sì ṣe àwọn àtúnṣe mìíràn. Àwọn àyípadà wọ̀nyí ni a ti ṣe láti mú ohun èlò náà wá sí ìbámu pẹ̀lú ìwífúnni onítàn tí ó péye jùlọ. Àwọn ìrí mìíràn tí àtúntẹ̀ titunjùlọ yìí ní nínú ni àwọn àwòrán tí a ti ṣe àgbéyẹ̀wò tí wọ́n nṣe àfihàn àwọn ibi aláwòrán pàtàkì nínú èyítí a ti gba àwọn ìfihàn, pẹ̀lú àwọn fọ́tò tí a ti mú dára síi ti àwọn ibi onítàn ti Ìjọ, àwọn atọ́ka sọ́tũn-sósì, àwọn àkọlé ìpín, ati àwọn àkékúrú àkòrí-ọ̀rọ̀, gbogbo èyítí ó jẹ́ pípèrò láti ran àwọn ònkàwé lọ́wọ́ láti ní òye àti láti yọ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìfiránṣẹ́ ti Olúwa bí a ṣe fi fúnni nínú Ẹ̀kọ́ ati àwọn Májẹ̀mú. Ìwífúnni fún àwọn àkọlé ìpín ni a ti mú láti inú Àfọwọ́kọ Ìwé Ìtàn Ìjọ àti History of the Church (Ìwé Ìtàn Ìjọ́) títẹ̀jáde (lápapọ̀ tí a ntọ́ka sí nínú àwọn àkọlé bíi ìtàn ti Joseph Smith) àti Joseph Smith Papers (Àwọn awẹ́ ìwé Joseph Smith). Ẹ̀KỌ́ ÀTI ÀWỌN MÁJẸ̀MÚ NÁÀ ÌPÍN 1 Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith ní ọjọ́ kínní Oṣù Kọkànlá ọdún 1831, ní àkókò àkànṣe ìpàdé kan tí àwọn alàgbà ìjọ ṣe ní Hiram, Ohio. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfihan ni a ti rígba láti ọwọ́ Olúwa sáájú àkókò yìí, àti pé àkójọpọ̀ ti àwọn wọ̀nyi fún títẹ̀ jade ní ẹ̀dà ìwé jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tí a gbà wọlé ní ìpàdé àpapọ̀ náà. Ìpín yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ ìsaájú ìwé Olúwa sí àwọn ẹ̀kọ́, àwọn májẹ̀mú, àti àwọn òfin tí a fi fúnni ní ìgbà yí. 1–7, Ohùn ìkìlọ̀ yíó wà fún gbogbo ènìyàn; 8–16, Ìṣubú kúrò nínú òtítọ́ àti ìwà búburú síwájú Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì; 17–23, Joseph Smith ni a pè lati mú òtítọ́ àti agbára Olúwa padà bọ̀ sípò lórí ilẹ̀ ayé; 24–33, Ìwé Ti Mọ́mọ́nì ni a mú jade tí a sì fi ìjọ òtítọ́ kalẹ̀; 34–36, A o mú àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé; 37–39, Wádìí àwọn òfin wọ̀nyi. 1 Ẹ fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin ènìyàn ìjọ mi, ni ohùn ẹnití ngbé ní ibi gíga, àti ẹnití ojú rẹ̀ wà lára gbogbo ènìyàn ńwí; Bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́ ni mo wí: Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn lati ọ̀nà jíjìn; àti ẹ̀yin tí ẹ wà lórí àwọn erékùsù òkun, ẹ jùmọ̀ tẹ́tísílẹ̀. 2 Nítorí lõtọ́ ni ohùn Olúwa nkọ sí gbogbo ènìyàn, kò sì sí ẹnikan tí yíò yọ; àti pé kì yíò sí ojú tí kì yíò rí, tàbí etí tí kì yíò gbọ́ tàbí ọkàn tí kì yíò wọnú rẹ̀. 3 Àti pé àwọn ọlọ̀tẹ̀ yíò gbọgbẹ́ ìbànújẹ́ púpọ̀, nítorí àwọn àìṣedẽdé wọn yíó di sísọ ní àwọn orí-ilé, àti àwọn ìṣe ìkọ̀kọ̀ wọn ni yíò di fífihàn. 4 Àti pé ohùn ìkìlọ̀ yíò wá fún gbogbo ènìyàn lati ẹnu àwọn ọmọ-ẹhìn mi, àwọn tí mo ti yàn ní awọn ọjọ́ ìkẹ́hìn yìí. 5 Àti pé wọn yíò jade lọ, ẹnikẹ́ni kì yíò sì dá wọn dúró, nítorí èmi Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. 6 Kíyèsíi, èyí jẹ́ àṣẹ mi, àti àṣẹ ti àwọn ìránṣẹ mi, àti ọ̀rọ̀ ìṣaájú mi sí ìwé àwọn òfin mi, èyí tí mo fi fún wọn lati tẹ̀ fún yin, Áà ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ ayé. 7 Nítorínáà, ẹ bẹ̀rù kí ẹ sì wárìrì, Áà ẹ̀yin ènìyàn, nítorí ohun tí èmi Olúwa ti pàṣẹ nínú wọn yíò wá sí ìmúṣẹ. 8 Àti pé lõtọ́ ni mo wí fún yin, pé àwọn tí wọ́n jade lọ, ní jíjẹ́ àwọn ìhìn wọ̀nyí fún àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé, àwọn ni a fi agbára fún lati fi èdídí dì lórí ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run, awọn aláìgbàgbọ́ àti awọn ọlọ̀tẹ̀; 9 Bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́, lati fi èdídí dì wọn títí di ọjọ́ náà nígbàtí ìbínú Ọlọ́run yíò di títú jade sí orí àwọn ènìyàn búburú láì ní òṣùnwọ̀n— 10 Títí di ọjọ́ tí Olúwa yíò dé lati san fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ rẹ̀, àti lati wọ̀n fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́bí òsùnwọ̀n tí òun ti fi wọ̀n fún arákùnrin rẹ̀. 11 Nítorínáà ohùn Olúwa nkọ sí awọn ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé, pé kí gbogbo àwọn tí ó bá fẹ́ gbọ́ lè gbọ́: 12 Ẹ múra, ẹ múra nítorí èyí tí ó mbọ̀, nítorí Olúwa súnmọ́ itosí; 13 Àti pé ìbínú Olúwa ti ru sókè, àti idà rẹ̀ ti di wíwẹ̀ ní ọ̀run, àti pé yíò ṣubú lórí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé. 14 Àti pé apá Olúwa yíò di fífihàn, ọjọ́ náà sì dé tán tí àwọn ẹnití kì yíò gbọ́ ohùn Olúwa, bẹ́ẹ̀ni ohùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni ní ṣíṣe àkíyèsí sí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì, yíò di kíké kúrò láàrin àwọn ènìyàn; 15 Nítorí wọ́n ti yapa kúrò ní àwọn ìlànà mi, wọn sì ti sẹ́ májẹ̀mú ayérayé mi; 16 Wọn kò wá Olúwa láti fi ẹsẹ̀ òdodo rẹ̀ múlẹ̀, ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn ńrìn ní ọ̀nà tirẹ̀, àti ní títẹ̀lé àwòrán ọlọ́run tirẹ̀, èyí tí àwòrán rẹ̀ wà ní ìrí ti ayé, àti èyí tí ohun ìní inú rẹ̀ jẹ́ ti òrìṣà kan, èyítí ó di ogbó tí yíò sì ṣègbé nínú Bábilónì, àní Babiloni nlá, èyítí yíò ṣubú. 17 Nítorínáà, èmi Olúwa, ní mímọ àwọn ewu tí yíò wá sí orí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé, ké pe ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, Kékeré, mo sì sọ̀rọ̀ sí i lati ọ̀run, mo sì fún un ní àwọn òfin; 18 Àti pé bákannáà mo fi àwọn òfin fún àwọn míràn, pé wọn nílati kéde àwọn nkan wọ̀nyi sí ayé; àti gbogbo eléyi kí ó lè wá sí ìmúṣẹ, èyítí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wolíì— 19 Àwọn ohun aláìlágbára ti ayé yíò jade wá, wọn yíó sì wó àwọn alágbára àti àwọn tí wọn ní ipá lulẹ̀, pé kí ènìyàn máṣe gba ọmọnìkejì rẹ̀ ní ìmọ̀ràn, bẹ́ẹ̀ni kí ó má gbẹ́kẹ̀lé apá ẹran ara— 20 Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù ènìyàn lè sọ̀rọ̀ ní orúkọ Ọlọ́run, tí í ṣe Olúwa, àní Olùgbàlà aráyé; 21 Kí ìgbàgbọ́ pẹ̀lú lè gbilẹ̀ nínú ilẹ̀ ayé. 22 Kí májẹ̀mú mi ti ayérayé lè fi ẹsẹ̀ múlẹ̀. 23 Kí á lè kéde ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi láti ẹnu aláìlagbára àti òpè sí àwọn òpin ayé, àti níwájú àwọn ọba àti àwọn alakoso. 24 Kíyèsíi, èmi ni Ọlọ́run, mo sì ti sọ ọ́; àwọn òfin wọ̀nyi jẹ́ tèmi, a sì fi wọn fún àwọn ìránṣẹ́ mi nínú àìlágbára wọn, ní irú èdè wọn, kí wọn ó lè ní òye. 25 Àti pé níwọnbí wọn bá ṣe àṣìṣe kí á lè sọọ́ di mímọ̀; 26 Àti pé níwọnbí wọn bá nwá ọgbọ́n kí á lè fún wọn ní ẹ̀kọ́; 27 Àti pé níwọ̀nbí wọn bá dẹ́ṣẹ̀ kí á lè bá wọn wí, kí wọn lè ronúpìwàdà. 28 Àti pe níwọnbí wọn bá ní ìrẹ̀lẹ̀ kí á lè sọ wọn di alágbára, àti kí a bùkún wọn láti òkè wá, kí wọn sì rí ìmọ̀ gbà láti àkókò dé àkókò. 29 Àti lẹ́hìn rírí àkọsílẹ̀ ti àwọn ará Néfì gbà, Bẹ́ẹ̀ni, àní ìránṣẹ mi Joseph Smith, Kékeré, lè ní agbára láti túmọ̀ Iwé ti Mọ́mọ́nì, nípa àánú Ọlọ́run, pẹ̀lú agbára Ọlọ́run. 30 Àti bákannáà àwọn ẹnití a fún ní àwọn òfin wọnyìí, lè ní agbára láti fi ìpìlẹ̀ ìjọ mi yìí lélẹ̀, àti láti mú-un jade kúrò nínú ìfarasin àti jáde kúrò nínú òkùnkùn, ìjọ kan ṣoṣo tí ó jẹ́ òtítọ́ àti alààyè lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, èyí tí Emi, Olúwa ní inú dídùn sí, ní sísọ̀rọ̀ sí ìjọ ní àpapọ̀ ati kì íṣe ẹni kọ̀ọ̀kan— 31 Nítorí èmi Olúwa kò lè bojúwo ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n ìyọ́nú tí ó kéré jùlọ; 32 Bí ó tilẹ̀ ríbẹ́ẹ̀, ẹnití ó bá ronúpìwàdà tí ó sì nṣe àwọn òfin Olúwa yíò rí ìdáríjì. 33 Àti ẹnití kò bá ronúpìwàdà, lọ́wọ́ rẹ̀ ni a ó ti gba àní ìmọ́lẹ̀ tí ó ti ní; nítorí Ẹmí mi kì yíò fi ìgbà gbogbo ja ìjàkadì pẹ̀lú ènìyàn, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí. 34 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yin, Áà ẹ̀yin olùgbé orí ilẹ̀ ayé: èmi Olúwa ní ìfẹ́ láti sọ gbogbo nkan wọ̀nyi di mímọ̀ sí gbogbo ẹlẹ́ran ara; 35 Nítorí èmi kìí ṣe ojúṣaájú ẹnikẹ́ni, àti kí gbogbo ènìyàn lè mọ̀ pé ọjọ́ náà dé kánkán; wákàtí náà kò tíì dé, ṣugbọ́n ó súnmọ́, nígbàtí a ó mú àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àti tí eṣù yíò ní agbára lórí ìjọba tirẹ̀. 36 Àti pé bákannáà, Olúwa yíò ní agbára lórí àwọn èniyàn mímọ́ rẹ̀, yíò sì jọba láàrin wọn, yíò sì sọ̀kalẹ̀ wá pẹ̀lú ìdajọ́ sí orí Idumea, tàbi ayé. 37 Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn òfin wọnyí, nítorí wọn jẹ́ òtítọ̀ àti òdodo, àti pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àti àwọn ìlérí tí ó wà nínú wọn gbogbo ni yíò wá sí ìmúṣẹ. 38 Ohun tí èmi Olúwa ti sọ, mo ti sọ, èmi kò sì tọrọ gáfárà fún ara mi, ati pé bí àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé bá tilẹ̀ kọjá lọ, ọ̀rọ̀ mi kì yíò kọjá lọ, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ yíò wá sí ìmúṣẹ, bóyá nípa ohùn tèmi tàbí ohùn àwọn ìránṣẹ mi, ọ̀kan náà ni. 39 Nítorí kíyèsíi, àti wòó, Olúwa ni Ọlọ́run, Ẹ̀mí sì jẹ́ri àkọsílẹ̀, àkọsílẹ̀ náà sì jẹ́ òtítọ́, àti pé òtítọ́ náà dúró láé ati títí láéláé. Amin. ÌPÍN 2 Àwọn ohun tí a fà yọ nínú ìwé ìtàn Joseph Smith ní ṣíṣe àtúnsọ àwọn ọ̀rọ ángẹ́lì Mórónì sí Wòlíì Joseph Smith, nígbàtí ó wà ní ilé bàbá Wòlíì ní Manchester, New York, ní ìrọ̀lẹ́ 21 Oṣù Kẹsãn 1823. Moroni ni ìkẹhìn nínú àwọn ọ̀pọ̀ ònkọ̀tàn tí wọn ti ṣe àkọsílẹ̀ èyí tí ó wà níwájú gbogbo ayé nísisìnyìí gẹ́gẹ́bí Ìwé Ti Mọ́mọ́nì. (Ṣe àfiwé Málákì 4:5–6; bákannáà ìpín 27:9; 110:13–16; àti 128:18.) 1, Elijah ni yíò fi oyè-àlùfáà hàn; 2–3, Àwọn ìlérí ti àwọn bàbá ni a gbìn sínú ọkàn àwọn ọmọ. 1 Kíyèsíi, èmi yíò fi oyè àlùfáà hàn sí ọ, láti ọwọ́ wòlíì Elijah, síwájú bíbọ̀ ọjọ́ nlá tí ó sì ní ẹ̀rù ti Olúwa. 2 Òun yíò sì gbìn sí ọkàn àwọn ọmọ awọn ìlérí tí a ṣe fún àwọn bàbá, ati ọkàn ti àwọn ọmọ yíò sì yí sí ọ̀dọ̀ àwọn bàbá wọn. 3 Bí èyí kò bá rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ilé ayé ni yíò di ìfiṣòfò ní bíbọ̀ rẹ̀. ÌPÍN 3 Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith, ní Harmony, Pennsylvania, ní oṣù Keje ọdún 1828, tí ó níí ṣe pẹ̀lú sísọnù ojú ewé ìwé mẹ́rindinlọgọ́fà tí a fi ọwọ́ kọ ìtumọ̀ rẹ̀ láti inú abala àkọ́kọ́ Ìwé Ti Mọ́mọ́nì, èyí tí a pè ní ìwé ti Lehi. Wòlíì náà ti fi ìlọ́ra fi ààyè sílẹ̀ kí àwọn ojú ewé ìwé náà kúrò ní ìpamọ́ rẹ̀ bọ́ sí ọ̀dọ̀ Martin Harris, ẹnití ó ti ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ bíi akọ̀wé nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ìfihàn yìí ni a fi fúnni nípasẹ̀ Urímù àti Túmímù. (Wo ìpín 10.) 1–4, Ipa ọ̀nà Olúwa jẹ́ ọ̀kan yípo ayeraye; 5–15, Joseph Smith gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà tàbi kí ó pàdánù ẹ̀bùn láti túmọ̀; 16–20, Ìwé Ti Mọ́mọ́nì wá láti gba irú ọmọ Léhì là. 1 Àwọn iṣẹ́, àti àwọn àgbékalẹ̀, àti àwọn èrò Ọlọ́run kò ṣeé bàjẹ́, wọn kò sì le di asán. 2 Nítorí Ọlọ́run kìí rìn ní àwọn ipa ọ̀nà tí ó wọ́, tàbí kí ó yà sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí sí òsì, òun kìí yípadà kúrò lórí ohun náà tí ó ti sọ, nítorínáà àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ́, ipa ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kan yípo ayérayé. 3 Ránti, rántí pé kìí ṣe iṣẹ́ ti Ọlọ́run ni a mú díbàjẹ́, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ti ènìyàn. 4 Nítorí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfihàn, àti agbára láti ṣe ọ̀pọlọpọ̀ iṣẹ́ títóbi, síbẹ̀ tí ó bá ńṣògo nínú ipá ti ara rẹ̀, tí ó sì ka awọn ìmọ̀ràn Ọlọ́run sí asán, tí ó sì ńtẹ̀lé àwọn èrò ti ara rẹ̀ àti ìfẹ́ ti ẹran ara, òun gbọdọ̀ ṣubú kí ó sì gba ẹ̀san Ọlọ́run òdodo sí orí rẹ̀. 5 Kíyèsíi, a ti fa àwọn ohun wọ̀nyí lé ọ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n báwo ni àwọn òfin rẹ ṣe le tó; kí o sì rántí bákannáà àwọn ìlérí tí a ṣe fún ọ, bí ìwọ kò bá ré wọn kọjá. 6 Àti pé kíyèsíi, ìgbà púpọ̀ ni o ti ré àwọn àṣẹ ati òfin Ọlọ́run kọjá, tí o sì ti tẹ̀síwájú nínú ìyílọ́kànpadà ti àwọn ènìyàn. 7 Nítorí, kíyèsíi, ìwọ kò nílati bẹ̀rù ènìyàn ju Ọlọ́run lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ènìyàn kò ka ìmọ̀ràn Ọlọ́run sí, síbẹ̀ wọn kẹ́gàn àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀— 8 Síbẹ̀ ó yẹ kí o jẹ́ olõtọ́, àti pé òun ìbá na apá rẹ̀ kí ó sì dáàbò bò ọ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọfà iná ọ̀tá; òun ìbá sì wà pẹ̀lú rẹ ní gbogbo ìgbà wàhálà. 9 Kíyèsíi, ìwọ ni Joseph, a sì ti yàn ìwọ láti ṣe iṣẹ́ Olúwa, ṣùgbọ́n nítorí ìrékọjá, bí ìwọ kò bá kíyèsára ìwọ yío ṣubú. 10 Ṣùgbọ́n rantí, aláànú ni Ọlọ́run, nítorínáà, ronúpìwàdà lórí ohun náà tí ìwọ ti ṣe èyítí ó lòdì sí òfin tí mo fi fún ọ, àti pé ìwọ náà ni a yàn síbẹ̀síbẹ̀, a sì tún ti pè ọ́ sí iṣẹ́ náà. 11 Bíkòṣepé ìwọ bá ṣe èyí, a o jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ ìwọ yíò sì dàbí àwọn ènìyàn míràn, ìwọ̀ kì yíò sì ní ẹ̀bùn mọ́. 12 Àti pé nígbàtí ìwọ bá jọ̀wọ́ ohun náà èyí tí Ọlọ́run ti fún ọ ní ìríran àti agbára láti túmọ̀, ìwọ jọ̀wọ́ ohun náà èyí tí ó jẹ́ mímọ́ sí ọwọ́ ènìyàn búburú, 13 Ẹnití ó ti ka àwọn ìmọràn Ọlọ́run sí asán, àti tí ó ti ṣẹ́ àwọn ìlérí mímọ́ jùlọ tí a ṣe níwájú Ọlọ́run, àti tí ó ti gbé ara lé ìdájọ́ ti ara rẹ̀ tí ó sì ṣògo nínú ọgbọ́n ti ara rẹ̀. 14 Àti pé èyí ni ìdí tí ìwọ fi pàdánù àwọn ànfaní rẹ fún ìgbà kan— 15 Nítorí ìwọ ti fi ààyè gba ìmọ̀ràn olùdarí rẹ lati di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ láti àtètèkọ́ṣe. 16 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ mi yíò mã tẹ̀ síwájú, níwọ̀nbí ìmọ̀ nípa Olùgbàlà kan ti di mímọ̀ fún ayé, nípasẹ̀ ẹ̀rí láti ẹnu àwọn Júù, àní bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ nípa Olùgbàlà kan yíò wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi— 17 Àti sí àwọn ará Néfì, àti àwọn ará Jákọ́bù, àti àwọn ará Jósefù, àti àwọn ará Sórámù nípasẹ̀ ẹ̀rí àwọn bàbá wọn— 18 Àti pé ẹ̀rí yìí yíò wá sí ìmọ àwọn ará Lámánì, àti àwọn ará Lẹ́múẹ́lì, àti àwọn Iṣmaẹ́lì, tí wọn ti rẹ̀hin nínú àìgbàgbọ́ nítorí àìṣedẽdé àwọn bàbá wọn, àwọn ẹnití Olúwa gbà láàyè láti pa àwọn arákùnrin wọn awọn ará Néfì run, nítorí àwọn àìṣedéédé àti àwọn ìríra wọn. 19 Àti pé nítorí ìdí èyí gãn ni a ṣe pa àwọn àwo wọ̀nyí mọ́, èyí tí ó ní àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí nínú—kí àwọn ìlérí Olúwa baà lè wá sí ìmúṣẹ, èyí tí ó ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀. 20 Àti pé kí àwọn ará Lámánì le ní ìmọ̀ nípa àwọn bàbá wọn, àti kí wọn le mọ àwọn ìlérí Olúwa, àti kí wọn le gbà ìhìnrere gbọ́ kí wọn ó sì le gbẹ́kẹ̀lé àwọn iṣẹ́ òdodo Jesu Kristi, ati kí wọn ó di ìṣelógo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀, àti pé nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà wọn kí a lè gbà wọ́n là. Amín. ÌPÍN 4 Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí bàbá rẹ̀, Joseph Smith Àgbà, ní Harmony, Pennsylvania, Oṣù kejì ọdún 1829. 1–4, Síṣe iṣẹ́-ìsìn akíkanjú kó àwọn ìránṣẹ́ Olúwa yọ; 5–6, Àwọn ìwà bĩ ti Ọlọ́run mú wọn yẹ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́; 7, Àwọn ohun ti Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ lílépa. 1 Nísisìyí kíyèsíi, isẹ́ ìyanu kan ti fẹ́ jáde wá láàrin àwọn ọmọ ènìyàn. 2 Nítorínáà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run, ẹ ríi wípé ẹ sìn-ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ipá, iyè àti okun, kí ẹ̀yin baà lè dúró láì ní ìdálẹ́bi níwájú Ọlọ́run ní ọjọ́ ìkẹhìn. 3 Nítorínáà, bí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ láti sin Ọlọ́run, a pè yìn sí iṣẹ́ náà; 4 Nítorí, kíyèsíi, oko ti funfun nísisìyí fún ìkórè; àti wòó, ẹnití ó bá sì fi dòjé rẹ̀ pẹ̀lú ipá rẹ̀, òun náà ni ó kórè sínú àká kí òun má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó mú ìgbàlà wá fún ẹ̀mí rẹ̀; 5 Àti pé ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ àti ìfẹ́, pẹ̀lú fífi ojú sí ògo Ọlọ́run nìkan, mú un yẹ fún iṣẹ́ náà. 6 Ẹ rántí ìgbàgbọ́, ìwà rere, ìmọ̀, àìrékọjá, sùúrù, inú rere sí ọmọnìkejì, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìrẹ̀lẹ̀, aápọn. 7 Ẹ béèrè, ẹ̀yin yíò sì rí gbà; ẹ kan ilẹ̀kùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. Àmín. ÌPÍN 5 Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní ìlú Harmony, Pennsyvania, Oṣù Kejì ọdún 1829, tí Martin Harris béèrè fún. 1–10, Ìran yìí yíò gba ọ̀rọ̀ Olúwa nípasẹ̀ Joseph Smith; 11–18, Àwọn ẹlẹ́ri mẹ́ta yíò jẹ́ri sí Ìwé Ti Mọ́mọ́nì; 19–20, A ó fi ẹsẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa múlẹ̀ bí ti awọn ìgbà ìṣaájú; 21–35, Martin Harris lè ronúpìwàdà kí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Ẹlérìí náà. 1 Kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé bí ìránṣẹ́ mi Martin Harris ṣe fẹ́ ẹ̀rí lati ọwọ́ mi, pé ìwọ, ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, Kékeré, ti gba àwọn àwo àkọsílẹ̀ náà èyí tí ìwọ ti jẹ́rìí sí, tí o sì kọ àkọsílẹ̀ pé o ti gbã lati ọ̀dọ̀ mi; 2 Àti nísisìyí, kíyèsíi, èyí ni ìwọ ó sọ fún un—ẹnití o bá ọ sọ̀rọ̀, sọ fún ọ pé: Èmi, Olúwa, èmi ni Ọlọ́run, mo sì ti fi àwọn nkan wọ̀nyí fún ọ, ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, Kékeré, mo sì ti pàṣẹ fún ọ pé o níláti dúró bíi ẹlérìí àwọn nkan wọ̀nyí. 3 Àti pé èmi ti mú kí ìwọ, pé o nílati wọ inú majẹ̀mú pẹ̀lú mi, pé ìwọ kì yíò fi hàn wọ́n bíkòṣe sí àwọn ènìyàn wọ̃nnì tí èmi ti pàṣẹ fún ọ; ìwọ kò sì ní agbára lórí wọn àyàfi bí mo bá fi í fún ọ. 4 Àti pé ìwọ ní ẹ̀bùn láti túmọ̀ àwọn àwo àkọsílẹ̀ náà; èyí sì jẹ́ ẹ̀bùn àkọ́kọ́ tí èmi fi fún ọ; àti pé mo ti paá láṣẹ pé ìwọ kò gbọdọ̀ ṣebí ẹnipé o ní ẹ̀bùn míràn títí tí èrò mi yíó fi wá sí ìmúṣẹ nípa èyìí; nítorí èmi kì yíò fi ẹ̀bùn míràn fún ọ títí tí yíò fi parí. 5 Lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé ègbé yíò wá sí ọ̀dọ̀ àwọn olùgbé orí ilẹ̀ bí wọn kò bá fetísílẹ̀ sí àwọ̀n ọ̀rọ̀ mi; 6 Nítorí lẹ́hìn àkókò yìí a ó yàn ọ́, ìwọ yíò sì jade lọ láti fi àwọn ọ̀rọ̀ mi fún àwọn ọmọ ènìyàn. 7 Kíyèsíi, bí wọn kò bá ní gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́, wọn kì yíò gbà ọ́ gbọ́, ìránṣẹ mi Joseph, bí ó bá ṣeéṣe pé kí ìwọ fi gbogbo àwọn ohun wọnyí hàn wọ́n tí èmi ti fà lé ọ lọ́wọ́. 8 Áà, ìran aláìgbàgbọ́ àti ọlọ́rùn líle yìí—ìbínú mi ru sókè sí wọn. 9 Kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, mo ti fi àwọn ohun wọ̃nnì pamọ́ èyítí mo ti fà fún ọ, ìránṣẹ́ mi Joseph, fún ìdí tí ó jẹ́ ọgbọ́n nínú mi, a ó sì fi í hàn fún àwọn ìran ọjọ́ iwájú. 10 Ṣùgbọ́n ìran yìí yíò gba ọ̀rọ̀ mi nípasẹ̀ rẹ. 11 Àti pé ní àfikún sí ẹ̀rí rẹ, ẹ̀rí láti ẹnu mẹ́ta nínú àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn tí èmi yíò pè tí n ó sì yàn, sí àwọn ẹnití èmi yíò fi àwọn ohun wọ̀nyí hàn, wọn yíò sì jade lọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ mi èyí tí a ó fi fúnni nípasẹ̀ rẹ. 12 Bẹ́ẹ̀ni, wọn yíò mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́, nítorí láti ọ̀run ni èmi yíò ti kéde rẹ̀ fún wọn. 13 Èmi yíò fún wọn ní agbára pé kí wọn le kíyèsíi kí wọn sì wo àwọn nkan wọ̀nyí bí wọn ṣe ri; 14 Àti pé ẹlòmíràn ni èmi kì yíò fún ní agbára yìí, láti gba ẹ̀rí yìí kannáà láàrin ìran yìí, nínú ìbẹ̀rẹ̀ ti ìgbédìde yìí àti ìjádewá ìjọ mi láti inú aginjù—kedere bíi òṣùpá, tí ó sì mọ́lẹ̀ bíi oòrùn, tí ó sì ní ẹ̀rù bíi ẹgbẹ́ ọmọ ogun pẹ̀lú àwọn àsìá. 15 Àti pé ẹ̀rí àwọn ẹlérìí mẹ́ta ni èmi yíò rán jade nípa ọ̀rọ̀ mi. 16 Àti pé kíyèsíi, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́, àwọn ni Emi yíò bẹ̀wò pẹ̀lú ìfarahàn Ẹ̀mí mi; wọn yíò sì di àtúnbí nípasẹ̀ mi, àní nípasẹ̀ omi àti Ẹ̀mí— 17 Àti pé ẹ̀yin gbọ́dọ̀ dúró fun ìgbà díẹ̀ kan síi, nítorí a kò tíì yàn yín— 18 Àti ẹ̀rí wọn náà yíò jade lọ bákannáà sí ìdálẹ́bi ìran yìí bí wọn bá sé ọkàn wọn le lòdì sí wọn; 19 Nítorí, pàsán ìsọdahoro yíò jade lọ sí ààrín àwọn olùgbé ilé ayé, yíò sì tẹ̀síwájú lati máa tú jade láti àkókò dé àkókò, bí wọn kò bá ronúpìwàdà, títí ilé ayé yíò fi di òfìfo, àti àwọn olùgbé rẹ̀ yíò fi jóná tán tí wọn yíò sì parun pátápátá nípa mímọ́lẹ̀ ti bíbọ̀ mi. 20 Kíyèsíi, mo sọ àwọn nkan wọ̀nyí fun yín, àní bí mo ṣe sọ fún àwọn ènìyàn bákannáà nípa ìparun Jerusalẹmu; àti pé ọ̀rọ̀ mi ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní àkókò yìí bí a ṣe fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ìgbà ìṣaájú. 21 Àti pé nísisìyí mo pàṣẹ fún ọ, ìwọ ìránṣẹ́ mi Joseph, láti ronúpìwàdà kí o sì rìn ní ìdúró ṣinṣin ní iwájú mi, kí o má sì ṣe fi ààyè gba ìyínilọ́kànpadà awọn ènìyàn mọ́. 22 Àti pé kí o dúró ṣinṣin nínú pípa àwọn òfin mọ́ pẹ̀lú èyítí èmi ti pàṣẹ fún ọ; bí o bá sì ṣe èyí, kíyèsíi, mo fún ọ ní ìyè ayérayé, àní bí wọn tilẹ̀ pa ọ́. 23 Àti pé nísisìyí, lẹ́ẹ̀kansíi, mo bá ọ sọ̀rọ̀, ìránṣẹ mi Joseph, nípa ọkùnrin náà tí ó fẹ́ ẹ̀rí— 24 Kíyèsíi, mo wí fún un, òun gbé ara rẹ̀ ga kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tó ní iwájú mi; ṣùgbọ́n bí òun bá lè tẹ orí ara rẹ̀ ba ní iwájú mi, tí ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nínú àdúrà nlá ati ìgbàgbọ́, nínú òtítọ́ ọkàn rẹ̀, nígbànáà ni èmi yíò fi fún un lati wo àwọn ohun tí ó ní ìfẹ́ láti rí. 25 Àti pé nígbànáà ni òun yíò sọ fún àwọn ènìyàn ìran yìí: Kíyèsíi, mo ti rí àwọn ohun tí Olúwa fi han Joseph Smith, Kekere, mo sì mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé wọ́n jẹ́ òtítọ́, nítorí mo ti rí wọn, nítorí a ti fi wọ́n hàn sí mi nípa agbára Ọlọ́run àti tí kìí ṣe ti ènìyàn. 26 Àti pé èmi Olúwa pàṣẹ fún un, ìránṣẹ́ mi Martin Harris, pé òun kì yíò sọ ohun kankan fún wọn mọ́ nípa àwọn ohun wọ̀nyí, àyàfi bí òun yíò sọ pé: mo ti rí wọn, a sì ti fi wọ́n hàn sí mí nípa agbára Ọlọ́run; ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí òun yíò sì sọ. 27 Ṣùgbọ́n bí òun bá sẹ́ èyìí òun yíò sẹ́ májẹ̀mú èyí tí ó ti dá pẹ̀lú mi ṣaájú, àti kíyèsíi, òun ti di ìdálẹbi. 28 Àti pé nísisìyí, àyàfi bí òun bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, tí òun sì jẹ́wọ́ fún mi àwọn ohun tí ó ti ṣe tí kò dára, àti kí ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú mi pé òun yíò pa àwọn òfin mi mọ́, àti pé òun yíò lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kíyèsíi, mo wí fún un, òun kì yíò ní irú ìran bẹ́ẹ̀, nítorí èmi kì yíò fi fún un lati wo awọn ohun náà nipa èyítí mo ti sọ̀rọ̀. 29 Àti pé bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, mo pàṣẹ fún ọ, ìránṣẹ́ mi Joseph, pé kí ìwọ ó sọ fún un, pé òun kì yíò ṣe ohunkóhun mọ́, tàbí kí ó yọ mí lẹ́nu mọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí. 30 Ati pé bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, kíyèsíi, mo wí fún ọ Joseph nígbàtí ìwọ bá ti túmọ̀ àwọn ojú ewé ìwé díẹ̀ síi ìwọ yíò dúró fún ìgbà kan, àní títí tí èmi yíò fi tún pàṣẹ fún ọ; nígbàyìí ni ìwọ ó tún le túmọ̀. 31 Àti pé àyàfi bí ìwọ bá ṣe èyí, kíyèsíi, ìwọ kì yíò ní ẹ̀bùn kankan mọ́, èmi yíò sì gba àwọn ohun tí mo ti fi pamọ́ pẹ̀lú rẹ lọ. 32 Àti pé nísisìyí, nítorípé mo rí i tẹ́lẹ̀, ète ti ó dúró láti pa ọ run, bẹ́ẹ̀ni, mo rí i tẹ́lẹ̀ pé bí ìránṣẹ́ mi Martin Harris kò bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì gba ẹ̀rí láti ọwọ́ mi, pé òun yíò ṣubú sínú ìrékọjá; 33 Àti pé àwọn púpọ̀ ni wọn ńdúró láti pa ọ́ run kúrò lórí ilẹ̀ ayé; àti nítorí ìdí èyí, kí ọjọ́ rẹ ó lè gùn, mo ti fún ọ ní àwọn òfin wọ̀nyí. 34 Bẹ́ẹ̀ni, fún ìdí èyí mo ti sọ pé: Dúró, kí o sì dúró jẹ́ẹ́ títí tí èmi ó fi pàṣẹ fún ọ, èmi yíò sì pèsè ọ̀nà àbáyọ nípa èyítí ìwọ yíò le ṣe àṣeyọrí ohun èyití mo ti paláṣẹ fún ọ. 35 Àti pé bí ìwọ bá jẹ́ olõtọ́ ní pípa àwọn òfin mi mọ́, a ó gbé ọ sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn. Amin. ÌPÍN 6 Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith àti Oliver Cowdery, ní Harmony, Pennsylvania, ní oṣù kẹrin ọdún 1829. Oliver Cowdery bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí akọ̀wé nínú títúmọ̀ Ìwé Ti Mọ́mọ́nì, Ọjọ́ keje oṣù kẹrin 1829. Oun ti gba ìṣípayá àtọ̀runwá tẹ́lẹ̀ nípa jíjẹ́ òtítọ́ ẹ̀rí ti Wòlíì, nípa àwọn àwo-àkọsílẹ̀ lórí èyí tí a fín àkọsílẹ̀ Ìwé Ti Mọ́mọ́nì sí. Wolíì náà béèrè lọ́wọ́ Olúwa nípasẹ̀ Urimù àti Tumimu òun sì gbà ìdáhùn yìí. 1–6, Àwọn òṣìṣẹ́ nínú oko Olúwa jẹ èrè ìgbàlà; 7–13, Kò sí ẹ̀bùn kan tí ó tóbi ju ẹ̀bùn ìgbàlà lọ; 14–27, Ẹ̀rí ti òtítọ́ máa ńjáde nípa agbára ti Ẹ̀mí; 28–37, Máa wo ọ̀dọ̀ Krísti, kí o sì máa ṣe rere láì dáwọ́ dúró. 1 Iṣẹ́ títóbi ati yíyanilẹ́nu kan ti fẹ́ jáde wá sí àwọn ọmọ ènìyàn. 2 Kíyèsíi, èmi ni Ọlọ́run; ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ mi, èyí tí ó jẹ́ aláàyè ati alágbára, ó mú ju idà olójú méjì lọ, fún pípín sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àwọn oríkẽ àti mùdùnmúdùn; nítorínáà ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn ọ̀rọ̀ mi. 3 Kíyèsíi, oko náà ti funfun tán fún ìkórè; nítorínáà ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti kórè, ẹ jẹ́ kí ó fi dòjé rẹ̀ pẹ̀lú ipá rẹ̀, àti kí ó kórè ní ojú ọjọ́, kí ó lè kó ìgbàlà àìlópin pamọ́ fún ọkàn rẹ̀ nínú ìjọba Ọlọ́run. 4 Bẹ́ẹ̀ni, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dòjé rẹ̀ tí ó sì kórè, òun náà ni Ọlọ́run pè. 5 Nítorínáà, bí ìwọ bá béèrè ní ọwọ́ mi, ìwọ yíò rí gbà; bí ìwọ bá kan ìlẹ̀kùn, a ó ṣí i fún ọ. 6 Nísisìyí, nítorítí ìwọ ti béèrè, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pa àwọn òfin mi mọ́, kí o sì lépa lati mú iṣẹ́ Síónì jáde wá ati lati fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. 7 Ma ṣe lépa fún ọrọ̀ ṣugbọ́n fún ọgbọ́n, àti kíyèsíi, àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run ni a ó ṣí fún ọ, àti nígbànáà ni a ó sọ ìwọ di ọlọ́rọ̀. Kíyèsíi, ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìyè ayérayé ni ọlọ́rọ̀. 8 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, gẹ́gẹ́bí ìwọ ṣe fẹ́ lati ọwọ́ mi bẹ́ẹ̀ ni yíò rí fún ọ; àti bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ yíó jẹ́ ohun èlò tí ṣíṣe rere púpọ̀ ní ìran yìí. 9 Ma ṣe sọ ohunkohun ṣùgbọ́n ironúpìwàdà fún ìran yìí; pa àwọn òfin mi mọ́, kí o sì ṣe àtìlẹ́hìn lati mú iṣẹ́ mi jáde wá; ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin mi, ìwọ yíò sì di alábùkúnfún. 10 Kíyèsíi, ìwọ ní ẹ̀bùn, àti pé alábùkúnfún ni ìwọ nítorí ẹ̀bùn rẹ. Rántí pé ó jẹ́ mímọ́ ó sì wá láti òkè— 11 Àti pé bí ìwọ bá béèrè, ìwọ yíò mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ títóbi àti yíyanilẹ́nu; nítorínáà ìwọ yíò lo ẹ̀bùn rẹ, kí ìwọ lè wá àwọn ohun ìjìnlẹ̀ rí, kí ìwọ lè mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí ìmọ̀ ti òtítọ́ náà, bẹ́ẹ̀ni, ní yí wọn lọ́kàn padà nínú àṣìṣe àwọn ọ̀nà wọn. 12 Máṣe sọ ẹ̀bùn rẹ di mímọ̀ fún ẹnikẹ́ni bíkòṣe àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lúù rẹ. Maṣe ka àwọn ohun mímọ́ sí yẹpẹrẹ. 13 Bí ìwọ yíò bá ṣe rere, Bẹ́ẹ̀ni, tí ìwọ yíò sì jẹ́ olõtọ́ títí dé òpin, a ó gbà ọ́ là ní ìjọba Ọlọ́run, èyí tí ó tóbi jùlọ nínú gbogbo awọn ẹ̀bùn Ọlọ́run; nítorí kò sí ẹ̀bùn kan tí ó tóbi ju ẹ̀bun ìgbàlà lọ. 14 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, alábùkúnfún ni ìwọ fún ohun tí ìwọ ti ṣe; nítorí ìwọ ti béèrè lọ́wọ́ mi, àti kíyèsíi, ní gbogbo ìgbà púpọ̀ tí ìwọ ti béèrè ìwọ ti gba ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí mi. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ kì bá tí wá sí ibi tí ìwọ wà ní àkókò yìí. 15 Kíyèsíi, ìwọ mọ̀ pé ìwọ ti béèrè lọ́wọ́ mi èmi sì fi òye yé ọkàn rẹ; àti pé nísisìyí èmi sọ àwọn nkan wọ̀nyí fún ọ kí ìwọ lè mọ̀ pé ati fi òye yé ọ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí òtítọ́; 16 Bẹ́ẹ̀ni, mo wí fún ọ, kí ìwọ kí ó le mọ̀ pé kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe Ọlọ́run tí ó mọ àwọn èrò àti ète ọkàn rẹ. 17 Mo sọ àwọn nkan wọ̀nyí fún ọ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí sí ọ—pé àwọn ọ̀rọ̀ tàbí iṣẹ́ èyítí o ti ńkọ jẹ́ òtítọ́. 18 Nítorínáà jẹ́ alãpọn; dúró ti ìránṣẹ́ mi Joseph, pẹ̀lú òtítọ́, nínú èyíkéyí ipò ìsòro tí òun lè wà nítorí ọ̀rọ̀ náà. 19 Kìlọ̀ fún un nínú àwọn àṣìṣe rẹ̀, àti bákannáà gba ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Jẹ́ onísùúrù; máa ronújinlẹ̀; wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì; ní sùúrù, ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́. 20 Kíyèsíi, ìwọ ni Oliver, mo sì ti bá ọ sọ̀rọ̀ nítorí àwọn ìfẹ́ ọkàn rẹ; nítorínáà fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pamọ́ sínú ọkàn rẹ. Jẹ́ olõtọ́ àti alãpọn ní pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, èmi yíò sì yí ọ ká pẹ̀lú apá ìfẹ́ mi. 21 Kíyèsíi, èmi ni Jésu Krísti, Ọmọ Ọlọ́run. Èmi yìí kan náà ni ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn tèmi, àwọn tèmi kò sì gbà mí. Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó ńtan nínú òkùnkùn, tí òkùnkùn náà kò sì borí rẹ̀. 22 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, bí ìwọ bá fẹ́ ẹ̀rí síwájú síi, mú ọkàn rẹ lọ sí òru ọjọ́ tí o kígbe pè mí nínú ọkàn rẹ, pé kí ìwọ le mọ̀ nípa òtítọ́ àwọn nkan wọ̀nyí. 23 Njẹ́ èmi kò ha sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí ọkàn rẹ nípa ohun náà? Irú ẹ̀rí títóbi wo ni o tún lè ní jù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lọ? 24 Àti nísisìyí, kíyèsíi, ìwọ ti gba ẹ̀rí kan; nítorí bí èmi bá ti sọ àwọn ohun tí ènìyàn kankan kò mọ̀, ìwọ kò ha ti gba ẹ̀rí kan bí? 25 Àti pé, kíyèsíi, mo ti fi ẹ̀bùn kan fún ọ, bí ìwọ bá fẹ́ láti ọ̀dọ̀ mi, láti lè túmọ̀, àní bíi ti ìránṣẹ mi Joseph. 26 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé àwọn àkọsílẹ̀ wà èyítí ó ní púpọ̀ lára àwọn ìhìnrere mi nínú, èyí tí a ti pamọ́ sẹ́hìn nítorí ìwà búbúrú àwọn ènìyàn. 27 Àti nísisìyí mo pàṣẹ fún ọ, pé bí o bá ní àwọn ìfẹ́ rere—ìfẹ́ láti to ìṣura jọ fún ara rẹ ní ọ̀run—nígbànáà ni ìwọ yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ ní mímú wá sí ìmọ́lẹ̀, pẹ̀lú ẹ̀bùn rẹ, àwọn abala wọ̃nnì lára àwọn ìwé mímọ́ mi tí a ti fipamọ́ nítorí àìṣedédé. 28 Àti nísisìyí, kíyèsíi, èmi fi fún ọ, àti bákannáà fún ìránṣẹ́ mi Joseph, àwọn kọ́kọ́rọ́ ẹ̀bùn yìí, èyí tí yíò mú iṣẹ́ ìranṣẹ́ yìí wá sí ìmọ́lẹ̀; àti pé ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó fi ìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀. 29 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, bí wọ́n bá kọ àwọn ọ̀rọ̀ mi, àti apákan ìhìnrere mi àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí, alábùkúnfún ni ẹ̀yin, nítorí wọn kò le ṣe síi yín mọ́ ju sí mi lọ. 30 Àní bí wọn bá sì ṣe síi yín aní bí wọn ti ṣe sí mi, alábùkúnfún ni ẹ̀yin, nítorí ẹ̀yin yíò gbé pẹ̀lú mi nínú ògo. 31 Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ àwọn ọ̀rọ̀ mi, èyí tí a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ẹ̀rí èyí tí a ó fi fúnni, alábùkúnfún ni àwọn, àti nígbànáà ni ẹ̀yin yíò ní ayọ̀ nínú èso àwọn iṣẹ́ yín. 32 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, gẹ́gẹ́bí mo ti wí fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi, níbi tí ẹni méjì tàbi mẹ́ta bá kó ara wọn jọ ní orúkọ mi, nípa ohun kan, kíyèsíi, níbẹ̀ ni èmi yíò wà lààrin wọn—àní bẹ́ẹ̀ni èmi ṣe wà lààrin yin. 33 Ẹ má ṣe bẹ̀rù láti ṣe rere, ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí ohunkohun tí ẹ̀yin bá fúrúgbìn, èyìínì náà ni ẹ̀yin yíò kórè; nítorínáà, bí ẹ̀yin bá fúrúgbìn rere ẹ̀yin yíò kórè rere gẹ́gẹ́bí èrè yín. 34 Nítorínáà, ẹ má bẹ̀rù, agbo kékeré, ẹ ṣe rere; ẹ jẹ́ kí ayé àti ọ̀run àpáàdì parapọ̀ ṣe òdì sí yín, nítorí bí a bá kọ́ọ yín lé orí àpáta mi, wọn kì yíò lè borí. 35 Kíyèsíi, èmi kò dá yín lẹ́bi; ẹ máa lọ ní àwọn ọ̀nà yín ẹ má sì ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́; ẹ ṣe àwọn iṣẹ́ tí mo pa láṣẹ fún yín pẹ̀lú àròjinlẹ̀. 36 Ẹ máa wo ọ̀dọ̀ mi nínú gbogbo èrò inú, ẹ má ṣe iyè méjì, ẹ má bẹ̀rù. 37 Ẹ kíyèsí àwọn ọgbẹ́ tí wọn gún ìhà mi, àti bákannáà àwọn àpá ìṣó tí ó wà ní awọn ọwọ́ àti ẹsẹ̀ mi; ẹ jẹ́ olõtọ́, ẹ pa àwọn òfin mi mọ́, ẹ̀yin yíò sì jogún ìjọba ọ̀run. Amin. ÌPÍN 7 Ìfihàn tí a fifún Wòlíì Joseph Smith àti Oliver Cowdery, ni Harmony, Pennsylvania, oṣù kẹrin ọdún 1829, nígbàtí wọn bèerè nípasẹ̀ Urímù àti Tummimù bóyá Johannu, àyànfẹ́ ọmọ ẹhìn, sì wà nínú ẹran ara tàbí o ti kú. Ìfihàn náà jẹ́ ìyípadà èdè ti irú àkọsílẹ̀ èyí tí Johannu ṣe sí orí awọ-ẹranko tí ó sì fi pamọ́ fúnra rẹ̀. 1–3, Jòhánnù àyànfẹ́ yíò wà láàyè títí tí Olúwa yíò fi dé; 4–8, Pétérù, Jamesì, àti Jòhánnù di àwọn kọ́kọ́rọ́ ìhìnrere mú. 1 Olúwa sì wí fún mi pé: Jòhánù, àyànfẹ́ mi, kín ni ìwọ nfẹ́? Nítorí bí ìwọ bá béèrè ohun tí o fẹ́, èmi yíò fií fún ọ. 2 Èmi sì wí fún un pé: Olúwa, fi agbára fún mi lórí ikú, kí èmi lè wà láàyè kí èmi sì mú awọn ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ. 3 Olúwa sì wí fún mi pé: Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, nítorítí ìwọ béèrè èyí, ìwọ yíò dúró títí èmi yíò fi dé nínú ògo mi, ìwọ yíò sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè àti ènìyàn. 4 Àti nítorí ìdí èyí Olúwa sọ fún Pétérù: Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi yíò fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ? Nítorí ó fẹ́ lati ọ̀dọ̀ mi pé kí òun lè mú àwọn ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n ìwọ nfẹ́ kí o lè yára wá sí ọ̀dọ̀ mi nínú ìjọba mi. 5 Èmi sọ fún ọ, Pétérù, èyí jẹ́ ìfẹ́-inú rere; ṣùgbọ́n àyànfẹ́ mi nfẹ́ pé kí òun lè ṣe púpọ̀ síi, tàbí iṣẹ́ tí ó tóbi síbẹ̀ lààrin àwọn ènìyàn ju èyí tí ó ti ṣe ṣíwájú. 6 Bẹ́ẹ̀ni, òun ti dáwọ́lé iṣẹ́ títóbi kan; nítorínáà èmi yíò ṣe òun bíi ọ̀wọ́ inà àti ángẹ́lì tí ó ńjíṣẹ́ ìrànṣẹ́; òun yíò ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn tí wọn yíò di ajogún ìgbàlà tí wọn ngbé ní ilé ayé. 7 Àti pé èmi yíò jẹ́ kí ìwọ ó ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ fún òun àti fún arákùnrin rẹ Jákọ́bù; àti ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ta ni èmi yíò fi agbára yìí àti àwọn kọ́kọ́rọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún títí èmi yíò fi dé. 8 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin méjèèjì yíò rí gbà gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú yín, nítorí ẹ ní ayọ̀ nínú ohun tí ẹ ti fẹ́. ÌPÍN 8 Ìfihan tí a fi fúnni nípasẹ Wòlíì Joseph Smith sí Oliver Cowdery, ní Harmony, Pennyslvania, Oṣù Kẹrin 1829. Nínú ipa iṣẹ́ títúmọ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Oliver, tí ó ntẹ̀síwájú gẹ́gẹ́bí akọ̀wé, ní kíkọ àwọn ohun tí Wòlíì npè, ní ìfẹ́-inú pé kí a bùn òun ní ẹ̀bùn ìtumọ̀. Olúwa dáhùn sí ẹbẹ̀ ọkàn rẹ̀ nípa fífúnni ní ìfihàn yìí. 1–5, Ìfihàn máa nwá nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, 6–12, Ìmọ̀ nípa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run àti agbára láti lè túmọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ ìgbàanì nwá nípa ìgbàgbọ́. 1 Oliver Cowdery, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé dájúdájú bí Olúwa ti wà láàyè, ẹnití í ṣe Ọlọ́run àti Olùràpadà rẹ, àní bẹ́ẹ̀ dájú ni ìwọ yíò gba ìmọ̀ ohun-kohun tí ìwọ yíò bá bèerè nínú ìgbàgbọ́ pẹ̀lú ọkàn òtítọ́, ní gbígbàgbọ́ pé ìwọ yíò gbà ìmọ̀ nípa àwọn àkọsílẹ̀ fífín ti àtijọ́, tí wọn jẹ́ ti igbàanì, tí wọn ní àwọn abala wọ̃nnì lára ìwé mímọ́ mi nínú, nípa èyí tí a ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ìṣípayá Ẹ̀mí mi. 2 Bẹ́ẹ̀ni, kíyèsíi, èmi yíò sọ fún ọ nínú ọkàn rẹ àti ní inú ẹ̀mí rẹ, lati ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí yíò wá sí orí rẹ àti èyí tí yíò máa gbé nínú ọkàn rẹ. 3 Nísisìyí, kíyèsíii èyí ni ẹ̀mí ìfihàn; kíyèsíi èyí náà ni ẹ̀mí nípasẹ̀ èyí tí Mósè fi mú àwọn ọmọ Israeli la Òkun Pupa kọjá ní orí ìyàngbẹ ilẹ̀. 4 Nítorínáà èyí ni ẹ̀bùn rẹ; ṣe àmúlò rẹ̀, àti pé alábùkúnfún ni ìwọ, nítorí èyí yíò gbà ọ́ sílẹ̀ ní ọwọ̀ àwọn ọ̀tá rẹ, nígbàtí, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, wọn yíò pa ọ́, kí wọn sì mú ọkàn rẹ wá sí ìparun. 5 Áà, rantí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kí o sì pa àwọn òfin mi mọ́. Rántí, èyí ni ẹ̀bùn rẹ. 6 Nísìsìyí èyí kìí ṣe gbogbo ẹ̀bùn rẹ; nítorí ìwọ tún ní ẹ̀bùn míràn, èyí tíí ṣe ẹ̀bùn Áárónì; kíyèsíi, èyí ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan fún ọ. 7 Kíyèsíi, kò sí agbára míràn, àfi agbára Ọlọ́run, tí ó lè mú kí ẹ̀bùn Áárónì yìí wà pẹ̀lú rẹ. 8 Nítorínáà, má ṣe iyè méjì, nítorí ẹ̀bùn Ọlọ́run ni; ìwọ yíò sì dìí mú ní ọwọ́ rẹ, láti ṣe àwọn iṣẹ́ yíyanilẹ́nu: àti pé kò sí agbára tí yíò lè gbàá kúrò ní ọwọ́ rẹ, nítorí iṣẹ́ Ọlọ́run ni. 9 Àti, nítorínáà, ohunkóhun tí ìwọ bá bèerè ní ọwọ́ mi pé kí èmi ó sọ fún ọ nípa ọ̀nà yìí, èyí ni èmi yíò fi fún ọ, ìwọ yíò sì ní ìmọ̀ nípa rẹ̀. 10 Rántí pé láì sí ìgbàgbọ́ ìwọ kò lè ṣe ohunkóhun, nítorínáà bèerè pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Má ṣe fi àwọn nkan wọ̀nyí ṣe eré; má ṣe bèerè fún èyí tí kò yẹ. 11 Béèrè kí ìwọ lè mọ̀ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, àti kí ìwọ baà lè túmọ̀ àti lati gba ìmọ̀ nínú gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ wọ̃nnì èyítí a ti fi pamọ́, tí wọn jẹ́ mímọ́; àti gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ rẹ ni a ó ṣe fún ọ. 12 Kíyèsíi, èmi ni Ẹnití Ó ti sọ ọ́; àti pé èmi kan náà ni ó ti bá ọ sọ̀rọ̀ láti àtètèkọ́ṣe. Àmin. ÌPÍN 9 Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Oliver Cowdery, ní Harmony, Pennsylvania, ní Oṣù Kẹ́rin 1829. Oliver ni a kìlọ̀ fún láti ní sùúrù a sì rọ̀ ọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn lati kọ̀wé, fún ìgbà kan ná, sí àpèkọ ẹnití ó ńtúmọ̀, dípò pé kí ó gbìdánwò láti túmọ̀. 1–6, Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ mìíràn ni a kò tíì túmọ̀; 7–14, Ìwé Ti Mọ́mọ́nì ni a túmọ̀ pẹ̀lú àṣàrò àti pẹ̀lú ìfìdímúlẹ̀ ti ẹ̀mí. 1 Kíyèsíi, mo wí fún ọ, ọmọ mi, pé nítorí tí ìwọ kò túmọ̀ gẹ́gẹ́bí èyíinì tí ìwọ fẹ́ lati ọ̀dọ̀ mi, àti bí o ṣe tún bẹ̀rẹ̀ láti máa kọ̀wé fún ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, Kékeré, àní bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èmi yíò fẹ́ kí o tẹ̀ síwájú títí ìwọ yíò fi parí àkọsílẹ̀ náà, èyí tí mo ti fi lé e lọ́wọ́. 2 Àti nígbànáà, kíyèsíi, àwọn àkọsílẹ̀ mìíràn ni mo ní, tí èmi yíò fún ọ ní agbára pé kí ìwọ le ṣe àtìlẹ́hìn lati túmọ̀. 3 Ṣe sùúrù, ọmọ mi, nítorí ó jẹ́ ọgbọ́n ní inú mi, àti pé kò tọ́nà pé kí o túmọ̀ ní àkókò yìí. 4 Kíyèsíi, iṣẹ́ tí a pè ọ́ láti ṣe ni láti kọ ìwé fún ìránṣẹ́ mi Joseph. 5 Àti, kíyèsíi, nítorípé ìwọ kò tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́bí o ṣe bẹ̀rẹ̀, nígbàtí o dáwọ́lé lati máa túmọ̀, ni mo ṣe gba ànfàní yìí kúrò ní ọwọ́ rẹ. 6 Má ṣe kùn sínú, ọmọ mi, nítorí ó jẹ́ ọgbọ́n nínú mi pé mo ti hùwà sí ọ ní ọ̀nà yìí. 7 Kíyèsíi, kò tíì yé ọ; ìwọ ti ní èrò pé èmi yíò fi í fún ọ, nígbàtí ìwọ kò ní èrò inú bíkòṣe pé kí o beèrè lọ́wọ́ mi. 8 Ṣùgbọ́n, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe àsàrò rẹ̀ nínú iyè rẹ; lẹ́hìnnáà ìwọ gbọ́dọ̀ bèerè lọ́wọ́ mi bóyá ó tọ́, bí ó bá sì tọ́, èmi yíò mú kí oókan àyà rẹ kí ó gbóná nínú rẹ; nítorínáà, ìwọ yíò mọ̀ lára pé ó tọ́. 9 Ṣùgbọ́n bí kò bá tọ́ ìwọ kì yíò ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀, ṣugbọ́n ìwọ yíò ní ìraníyè ti ìrònú èyí tí yíò mú kí o gbàgbé ohun tí ó jẹ́ àìtọ́; nítorínáà, ìwọ kò leè kọ ohun náà tí ó jẹ́ mímọ́ àfi bí a bá fi fún ọ láti ọ̀dọ̀ mi. 10 Nísisìyí, bí ìwọ bá ti mọ èyí ìwọ ìba ti túmọ; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò tọ̀nà pé kí o túmọ̀ ní ìsisìyí. 11 Kíyèsíi, ó tọ̀nà nígbàtí o bẹ̀rẹ̀; ṣùgbọ́n ìwọ bẹ̀rù, àti pé àkókò náà ti kọjá, kò sì tọ̀nà mọ́ nísìsìyí; 12 Nítorí, njẹ́ ìwọ kò kíyèsíi pé mo ti fun ìránṣẹ mi Joseph ní ànító okun, nípa èyí tí àlàfo náà dí? Kò sì sí ọ̀kankan nínú yin tí mo dá lẹ́bi. 13 Ṣe ohun yìí èyí tí èmi ti paláṣẹ fún ọ, ìwọ yíò sì ṣe rere. Jẹ́ olõtọ́, kí o má sì ṣe gba ìdánwò láàyè. 14 Dúró ṣinṣin nínú iṣẹ́ náà èyí tí mo ti pè ọ́ sí, àti pé irun orí rẹ kan kì yíò sọnù, a ó sì gbé ọ sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn. Amin. ÌPÍN 10 Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith, ní Harmony, Pennsylvania, tí ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ àyíká Oṣù Kẹrin 1829, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn abala kan le ti jẹ́ gbígbà láti ìbẹ̀rẹ̀ bíi ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1828. Nínú èyí Olúwa sọ fún Joseph nípa àwọn àtúnṣe tí àwọn ènìyàn búburú ṣe nínú àwọn ojú ewé ìwé àfọwọ́kọ mẹ́rìndínlọ́gọ́fà lati ínú ìtumọ̀ ìwé ti Léhì, nínú Ìwé Ti Mọ́mọ́nì. Àwọn ojú ewé ìwé àfọwọ́kọ wọ̀nyí ti sọnù ní ìpamọ́ Martin Harris, ẹnití a fa àwọn ewé ìwé náà lé lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀. (Wo àkọlé sí ìpín kẹta.) Ète búburú náà ni láti dúró de àtúnṣe tí wọ́n retí sí ìtúmọ̀ àwọn ohun tí ó wà nínú àwọn ojú ewé ìwé tí wọ́n jí gbé lọ, àti lẹ́hìnnáà kí wọn ó le sọ olùtúmọ̀ di aláìmọ̀kan nípa fífi àwọn àìṣedéédé hàn tí àwọn àtúnṣe náà ti múwá. Pé ète búburú yìí ti di rírò sínú fún ènìyàn ibi náà ti ó sì jẹ́ mímọ̀ sí Olúwa àní nígbàtí Mọ́mọ́nì, ará Néfì olùpìtàn ìgbàanì, nṣe àkekúrú àwọn àwo tí a ti kójọ sílẹ̀, ni ó fara hàn nínú Ìwé Ti Mọ́mọ́nì (wo Àwọn Ọ̀rọ̀ ti Mọ́mọ́nì 1:3–7). 1–26, Sátánì rú àwọn ènìyàn búburú sókè láti ṣe àtakò iṣẹ́ Olúwa; 27–33, Òun nwá láti pa ọkàn àwọn ènìyàn run; 34–52, Ìhìnrere yíò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Lámánì àti sí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè nípa Ìwé Ti Mọ́mọ́nì; 53–63, Olúwa yíò gbé Ìjọ Rẹ̀ àti ìhìnrere Rẹ̀ kalẹ̀ ní ààrin àwọn ènìyàn; 64–70, Òun yíò kó gbogbo àwọn ẹni ironúpìwàdà jọ sí inú Ìjọ Rẹ̀ yíò sì gba àwọn olùgbọ́ràn là. 1 Nísisìyí, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé nítorí tí o gbé àwọn ohun kíkọ wọ̃nnì tí a ti fi agbára fún ọ láti túmọ̀ nípasẹ̀ Urímù àti Túmmímù, sílẹ̀ sí ọwọ́ ènìyàn búburú, ìwọ ti sọ wọ́n nù. 2 Àti pé ìwọ ti sọ ẹ̀bùn rẹ nù ní ìgbà kannáà, iyè rẹ sì ti ṣókùnkùn. 3 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nísisìyí a ti mú un padà sípò fún ọ lẹ́ẹ̀kansíi; nítorínáà ríi pé o jẹ́ olótĩtọ́ kí o sì tẹ̀síwájú sí píparí ìyókù iṣẹ́ ìtumọ̀ náà gẹ́gẹ́bí o ṣe bẹ̀rẹ̀. 4 Má ṣe sáré púpọ̀ jù tàbí kí o ṣe iṣẹ́ ju bí o ti ní okun lọ àti àwọn ohun èlò tí a pèsè fún ọ láti ṣe ìtúmọ̀; ṣugbọ́n jẹ́ aláìṣemẹ́lẹ́ títí dé òpin. 5 Máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ìwọ lè di aṣẹ́gun; Bẹ́ẹ̀ni, kí ìwọ o lè ṣẹ́gun Sátánì, àti pé kí ìwọ lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Sátánì tí wọ́n di iṣẹ́ rẹ̀ mú. 6 Kíyèsíi, wọn ti wá ọ̀nà láti pa ọ́ run; Bẹ́ẹ̀ni, àní ẹni náà nínú ẹni tí ìwọ ní ìgbẹkẹ̀lé, ti wá ọ̀nà láti pa ọ́ run. 7 Àti pé fún ìdí èyí mo sọ pé ó jẹ́ ènìyàn búburú, nítorí òun ti wá ọ̀nà láti kó àwọn ohun tí a fi sí ìpamọ́ rẹ lọ; àti bákannáà òun ti lépa láti pa ẹ̀bùn rẹ run. 8 Àti pé nítorí tí ìwọ ti gbé àwọn ìwé náà lé e lọ́wọ́, kíyèsíi, àwọn ènìyàn búburú ti gbà wọ́n lọ́wọ́ rẹ. 9 Nítorínáà, ìwọ ti gbé àwọn nkan wọ̀nyí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, èyíinì tí ó jẹ́ mímọ́, sí inũ búburú. 10 Àti pé, kíyèsíi, Sátánì ti fi sí ọkàn wọn láti pààrọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí ìwọ ti mú kí a kọ, tàbí tí ìwọ ti túmọ̀, àwọn èyí tí wọn ti lọ kúrò ní ọwọ́ rẹ. 11 Àti kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé nítorí tí wọn ti pààrọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọn kà lòdì sí ohun tí ìwọ túmọ̀ àti tí o mú kí a kọ; 12 Àti, ní ọ̀nà yìí, Sátánì ti lépa lati gbé ète àrékérekè kan kalẹ̀, kí òun lè pa iṣẹ́ yìí run. 13 Nítorí ó ti fi sí ọkàn wọn láti ṣe èyí, pé nípa irọ́ pípa wọn yíò lè sọ pé àwọn ti mú ọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí ìwọ ṣe bí ẹni pé o túmọ̀. 14 Lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé èmi kì yíò fi ààyè gbà pé kí Sátánì ṣe àṣeyọrí ète ibi rẹ̀ nínú ohun yìí. 15 Nítorí kíyèsíi, òun ti fi sí ọkàn wọn láti mú kí ìwọ ó dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò, nípa bíbéèrè lati tún ìtúmọ̀ rẹ̀ ṣe lẹ́ẹ̀kan síi. 16 Àti nígbànáà, kíyèsíi, wọ́n sọ wọ́n sì rò nínú ọkàn wọn—Àwa yíò wòó bóyá Ọlọ́run ti fún un ní agbára láti túmọ̀, bí ó bá sì rí bẹ́ẹ̀, yíò tún fún un ní agbára bákanáà lẹ́ẹ̀kan síi. 17 Àti pé bí Ọlọ́run bá fún un ní agbára lẹ́ẹ̀kan síi, tàbí bí òun bá ṣe ìtúmọ̀ lẹ́ẹ̀kansíi, tàbí, ní ọnà míràn, bí òun bá lè mú awọn ọ̀rọ̀ kannáà jáde wá, kíyèsíi, a ti ní àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọwọ́ wa, àwa sì ti pààrọ̀ wọn; 18 Nítorínáà wọn kò lè bá ara mu, àwa yíò sì sọ pé òun ti pa irọ́ nínú awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti pè òun kò ní ẹ̀bùn, òun kò sì ní agbára. 19 Nítorínáà a ó paárun, àti iṣẹ́ náà bákannáà; àti pé a ó ṣe èyí kí ojú má baà tì wá ní ìkẹhìn, àti kí á ba lè gba ògo ti ayé. 20 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé Sátánì ti gba ọkàn wọn; ó rú ọkàn wọn sókè sí àìṣedéédé ní ìlòdì sí ohun èyítí ó dára; 21 Àti pé ọkàn wọn ti bàjẹ́, ó sì kún fún búburú àti àwọn ohun ìríra; àti pé wọn fẹ́ràn òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, nítorí awọn iṣẹ́ wọn jẹ́ ibi; nítorínáà wọn kì yíò béèrè mi. 22 Sátánì rú wọn sókè, kí ó lè sìn ọkàn wọn lọ sí ìparun. 23 Àti báyìí ni òun ti gbé ète àrékérekè kan kalẹ̀, ní ríro láti pa iṣẹ́ Ọlọ́run run; ṣugbọ́n èmi yíò beerè èyí ní ọwọ́ wọn, yíò sì padà di ìtìjú àti ìdálẹ́bi fún wọn ní ọjọ́ ìdájọ́. 24 Bẹ́ẹ̀ni, òun ti rú ọ̀kàn wọ́n sókè láti bínú tako iṣẹ́ yìí. 25 Bẹ́ẹ̀ni, òun ti sọ fún wọn: Ẹ tàn jẹ kí ẹ sì dúró ní ìkọ̀kọ̀ láti mú, kí ẹ lè pa run; kíyèsíi; èyí kìí ṣe ìbàjẹ́. Àti báyìí ni òun pọ́n wọn, ó sì wí fún wọn pé kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ lati pa irọ́ kí wọ́n ba lè mú ènìyàn nínú irọ́, kí wọ́n ba lè pa á run. 26 Àti báyìí ni ó pọ́n wọn lé, ó sì sìn wọn títí ó fi wọ́ ọkàn wọn lọ sí ọ̀run àpáàdì; àti báyìí ni ó jẹ́ kí wọn ó mú ara wọn bọ́ sínú ìkẹ́kùn tí àwọn tìkara wọn dẹ. 27 Àti báyìí ni òun nlọ sí òkè àti sí ilẹ̀, síwá àti sẹ́hìn nínú ilé ayé, ní wíwá lati pa ọkàn àwọn ènìyàn run. 28 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, ègbé ni fún ẹnití ó parọ́ láti tan ni jẹ nítorí òun rò pé ẹlòmíràn ti parọ́ láti tan ni jẹ, nítorí a kì yíò dá irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí nínú ìdájọ́ Ọlọ́run. 29 Nísisìyí, kíyèsíi, wọ́n ti pààrọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nítorípé Sátánì wí fún wọn: Òun ti tàn ọ́ jẹ—àti pé báyìí ni ó pọ́n wọn sí ìṣìnà lati ṣe àìṣedéédé, láti jẹ́ kí ìwọ kí ó dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò. 30 Kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé ìwọ kì yíò tún túmọ̀ lẹ́ẹ̀kansíi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̃nnì tí o ti jáde lọ kúrò ní ọwọ́ rẹ. 31 Nitori, kíyèsíi, wọn kì yíò ṣe àṣeyọrí awọn ète ibi wọn ní pípa irọ́ lòdì sí àwọn ọ̀rọ wọ̃nnì. Nítorí, kíyèsíi, bí ìwọ bá le mú àwọn ọ̀rọ̀ kannáà jade, wọ́n yíò sọ pé ìwọ ti pa irọ́, àti pé ìwọ ti ṣe bíi ẹnipé o túmọ̀, ṣùgbọ́n pé o ti tako ara rẹ. 32 Àti, kíyèsíi, wọn yíò tẹ èyí jade, àti pé Sátánì yíò sé ọkàn àwọn ènìyàn le láti ru wọ́n sókè lati bínú lòdì sí ọ, kí wọn má baà gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́. 33 Báyìí ni Sátánì ronú láti fi agbára tẹ ẹ̀rí rẹ mọ́lẹ̀ ní ìran yìí, pé kí iṣẹ́ náà má baà lè jade wá ní ìran yìí. 34 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, ọgbọ́n nìyí, àti nítorí tí mo fi ọgbọ́n hàn ọ́, tí mo sì fún ọ ní àwọn òfin nípa àwọn nkan wọ̀nyí, ohun tí ìwọ yíò ṣe, má ṣe fi hàn sí ayé títí tí ìwọ yíò fi ṣe àṣeyọrí iṣẹ́ ìtumọ̀ náà. 35 Kí ó má yà ọ lẹ́nu pé mo wí fún ọ: Ọgbọ́n nìyí, má ṣe fi hàn sí ayé—nítorí mo wí, má ṣe fi hàn sí ayé, kí á lè pa ọ́ mọ́. 36 Kíyèsíi, èmi kò sọ pé ìwọ kò ní fi hàn àwọn olódodo. 37 Ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbàtí ìwọ kò lè fi ìgbà gbogbo ṣe ìdájọ́ olódodo, tàbí níwọ̀n ìgbàtí ìwọ kò lè fi ìgbà gbogbo mọ ẹni búburú yàtọ̀ sí olódodo, nítorínáà mo wí fún ọ, pa ẹnu rẹ mọ́ títí tí èmi yíò fi ríi pé ó tọ́ láti sọ ohun gbogbo di mímọ̀ sí ayé nípa ohun náà. 38 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, pé àkọsílẹ̀ àwọn ohun wọ̃nnì tí ìwọ ti kọ, èyítí o ti lọ kúrò ní ọwọ́ rẹ, wà ní fífín sí orí àwọn àwo ti Néfì; 39 Bẹ́ẹ̀ni, kí o sì rantí pé a ti sọ nínú àwọn ìwé kíkọ pé àwọn àkọsílẹ̀ pàtàkì kan ni a ti fi fúnni nípa àwọn ohun wọ̀nyí ní orí àwọn àwo Néfì. 40 Àti nísisìyí, nítori àkọsílẹ̀ èyí tí a fín sí orí àwọn àwo ti Néfì ṣe pàtàkì jùlọ nípa àwọn ohun tí, nínú ọgbọ́n mi, èmi yíó mú wá sí ìmọ̀ àwọn ènìyàn nínú àkọsílẹ̀ yìí— 41 Nítorínáà, ìwọ yíò tumọ̀ àwọn ìfín tí wọn wà ní orí àwọn àwo ti Néfì, sí ìsàlẹ̀ àní títí tí ìwọ yíò fi dé àkókò ìjọba ọba Bẹ́njámẹ́nì, tàbí títí ìwọ yíò fi dé ibi tí ìwọ túmọ̀ dé, àwọn èyí tí ìwọ ti dá dúró sí ọwọ́; 42 Àti kíyèsíi, ìwọ yíò tẹ̀ẹ́ jade gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ti Néfì; àti báyìí èmi yíò dà àwọn wọ̃nnì láàmú tí wọn yí àwọn ọ̀rọ̀ mi padà. 43 Èmi kì yíò fi ààyè sílẹ̀ pé kí wọn ba iṣẹ́ mi jẹ́; Bẹ́ẹ̀ni, èmi yíò fi hàn sí wọn pé ọgbọ́n ti èmi ga ju àrékérekè ti èṣù lọ. 44 Kíyèsíi, abala kan péré ni wọ́n ti gbà, tàbí akékúrú ti àkọsílẹ̀ ti Néfì. 45 Kíyèsíi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ni a fín sí orí àwọn àwo ti Néfì èyí tí ó fúnni ní òye títóbi jù lórí ìhìnrere mi; nítorínáà, èyí jẹ́ ọgbọ́n nínú mi pé kí ìwọ ó túmọ̀ abala kìnní ti àwọn ìfín tí Néfì yìí, kí o sì rán jáde nínú iṣẹ́ yìí. 46 Àti, kíyèsíi, gbogbo ìyókù iṣẹ́ yìí ní gbogbo àwọn abala ìhìnrere mi nínú, èyí tí àwọn wòlíì mímọ́ mi; bẹ́ẹ̀ni, ati bákannáà àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi, ti fẹ́ nínú àdúrà wọn pé kí wọ́n lè jáde wá sí àwọn ènìyàn wọ̀nyìí. 47 Àti pé mo wí fún wọn, pé a ó fi fún wọn gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn nínú àwọn àdúrà wọn; 48 Bẹ́ẹ̀ni, èyí sì ni ìgbàgbọ́ wọn—pé ìhìnrere mi, èyí tí mo fi fún wọn pé kí wọn lè máa wàásù rẹ̀ ní ọjọ́ ayé wọn, lè wá sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn àwọn ará Lámánì, àti bákannáà gbogbo àwọn tí wọn ti di ara Lámánì nípa ìyapa wọn. 49 Nísisìyí, èyí nìkan kọ́—ìgbàgbọ́ wọn nínú àwọn àdúrà wọn ni pé kí ìhìnrere yìí lè di mímọ̀ bákannáà, bí ó bá jẹ́ pé ó ṣeéṣe pé kí àwọn orílẹ̀ èdè míràn ó ní ilẹ̀ yìí ní ìní; 50 Àti báyìí ni, wọ́n fi ìbùkún sílẹ̀ sí orí ilẹ̀ yìí nínú àwọn àdúrà wọn, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ìhìnrere yìí gbọ́ ní ilẹ̀ yìí lè ní ìyè ayérayé; 51 Bẹ́ẹ̀ni, pé kí ó lè jẹ́ ọ̀fẹ́ sí gbogbo èyíkéyìí orílẹ̀ èdè, ìbátan, èdè, tàbí ènìyàn tí wọ́n lè jẹ́. 52 Àti nísisìyí, kíyèsíi, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn nínú àdúrà wọn ni èmi yíò mú abala yìí ti ìhìnrere mi wá sí ìmọ̀ àwọn ènìyàn mi. Kíyèsíi, èmi kò mú un wá láti pa èyíinì run tí wọ́n ti gbà, ṣùgbọ́n láti gbé e ró. 53 Àti nítorí èyí ni èmi ti wí pé: Bí ìran yìí kò bá sé ọkàn wọn le, èmi yíò gbé ìjọ mi kalẹ̀ ní ààrin wọn. 54 Nísisìyí, èmi kò sọ èyí láti pa ìjọ mi run, ṣùgbọ́n mo sọ èyí láti gbé ìjọ mi ró; 55 Nítorínáà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ti ìjọ mi kí ó máṣe bẹ̀rù, nítorí irú wọn yíò jogún ìjọba ọ̀run. 56 Ṣùgbọ́n àwọn ẹnití kò bẹ̀rù mi, tàbí pa àwọn òfin mi mọ́ ṣùgbọ́n tí wọn kọ́ àwọn ìjọ fún ara wọn fún èrè jíjẹ, bẹ́ẹ̀ni, àti gbogbo àwọn wọ̃nnì tí wọn nṣe búburú tí wọn ngbé ìjọba èṣù ró—bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé àwọn ni èmi yíò dí lọ́wọ́, èmi yíó mú kí wọn ó wárìrì àti wọn yíò sì gbọ̀n dé ààrin gbùngbùn. 57 Kíyèsíi, èmi ni Jésu Krísti ọmọ Ọlọ́run. Mo wá sí ọ̀dọ̀ àwọn tèmi, àwọn tèmi kò sì gbà mí. 58 Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó ńtàn nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì mọ̀ ọ́. 59 Èmi ni ẹni náà tí ó sọ—Àwọn àgùntàn míràn ni emi ní tí wọn kìi ṣe ti agbo yìí—fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi, àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni wọ́n wà tí ọ̀rọ̀ mi kò yé. 60 Àti pé èmi yíò fi hàn àwọn ènìyàn yìí pé mo ní àwọn àgùntàn míràn, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀ka ti ilé Jakọbù; 61 Àti pé èmi yíò mú un wá sí ìmọ́lẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu wọn, tí wọn ṣe ní orúkọ mi. 62 Bẹ́ẹ̀ni, èmi yíò sì mú ìhìnrere mi wá sí ìmọ́lẹ̀ bákannáà, èyí tí a ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ fún wọn, àti, kíyèsíi, wọn kí yíò sẹ́ àwọn ohun náà èyítí o ti gbà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbé e ró, wọn yíò sì mú un wá sí ìmọ́lẹ̀ àwọn kókó òtítọ́ ẹ̀kọ́ mi, bẹ́ẹ̀ni, àti ẹ̀kọ́ kansoso tí ó wà nínú mi. 63 Àti pé èyí ni mo ṣe kí èmi ó lè gbé ìhìnrere mi kalẹ̀, kí á má baà rí ìjà púpọ̀, bẹ́ẹ̀ni, Sátánì máa ńru ọkàn àwọn ènìyàn sókè sí ìjà nípa àwọn kókó ẹ̀kọ́ mi, àti nínú àwọn nkan wọ̀nyí wọn nṣe àṣìṣse, nítorí wọn ńyí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run po òye rẹ̀ kò sì yé wọn. 64 Nítorínáà, èmi yíò sọ ohun ìjìnlẹ̀ nlá yìí di mímọ̀ fún wọn. 65 Nítorí, kíyèsíi, èmi yíò kó wọn jọ bí àgbébọ̀ ti íràdọ̀ bò àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀, bí wọn kò bá sé ọkàn wọn le. 66 Bẹ́ẹ̀ni, bí wọn yíò bá wá, wọ́n lè wá, kí wọn o sì ṣe àbápín nínú omi ìyè ayérayé lọ́fẹ̀ẹ́. 67 Kíyèsíi, èyí ni ẹ̀kọ́ mi—ẹnikẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà tí ó sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun kannáà ni ìjọ mi. 68 Ẹnikẹ́ni tí ó bá kéde púpọ̀ tàbí kéré jù èyí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kìí ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ alátakò sí mi, nítorínáà kìí ṣe ti ìjọ mi. 69 Àti Nísisìyí, kíyèsíi, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ti ìjọ mi, ati tí ó fi ara da ìjọ mi títí dé òpin, òun ni èmi yíò gbé kalẹ̀ lórí àpáta mi, ọ̀run àpádì kì yíò sì lè dáa dúró. 70 Àti nísisìyí, rantí àwọn ọ̀rọ̀ ẹni náà tí íṣe ìyè àti ìmọ́lẹ̀ ayé, Olùràpadà rẹ, Olúwa rẹ àti Ọlọ́run rẹ. Amin. ÌPÍN 11 Ìfihàn tí a fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí arákùnrin rẹ̀ Hyrum Smith, ní Harmony, Pennsylvania, Oṣù Karũn 1829. Ìfihàn yìí jẹ́ èyí tí a gbà nípa lílo Urimù àti Tummimù ní ìdáhùn sí àdúrà àti ìbéèrè Joseph. Ìtàn ti Joseph Smith dáa lábàá pé a gba ìfihàn yìí lẹ́hìn ìmúpadàbọ̀sípò Oyè Àlufáà ti Aaronì. 1–6, Àwọn òṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajarà yíò jẹ èrè ìgbàlà; 7–14, Wá ọgbọ́n, kígbe ironúpìwàdà, ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ẹ̀mì, 15–22, Pa àwọn òfin mọ́, kí o sì ṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Olúwa; 23–27, Má ṣe sẹ́ ẹ̀mí ìfihàn àti ìsọtẹ́lẹ̀; 28–30, Àwọn tí wọ́n gba Krísti di ọmọ Ọlọ́run. 1 Iṣẹ́ títóbi ati yíyanilẹ́nu kan ti fẹ́ jáde wá ní àárin àwọn ọmọ ènìyàn. 2 Kíyèsíi, èmi ni Ọlọ́run; tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, èyí tí ó jẹ́ alààyè ati alágbára, ó mú ju idà olójú méjì lọ, sí pípín lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ti oríkèé àti mùndùnmúndùn; nítorínáà tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi. 3 Kíyèsíi, oko náà ti funfun tán fún ìkórè; nítorínáà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti kórè ẹ jẹ́ kí ó fi dòjé rẹ̀ pẹ̀lú agbára rẹ̀, kí ó sì kórè nígbatí ọjọ́ sì wà, kí òun baà lè fi pamọ́ fún ìgbàlà àìlópin ti ẹ̀mí rẹ̀ ní ìjọba Ọlọ́run. 4 Bẹ́ẹ̀ni, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dòjé rẹ̀ gún un tí ó sì kórè, ẹni náà ni Ọlọ́run pè. 5 Nítorínáà, bí ìwọ bá béèrè ní ọwọ́ mi, ìwọ yíò rí gbà; bí ìwọ bá kan ìlẹ̀kùn, a ó ṣí i fún ọ. 6 Nísisìyí, bí ìwọ ti béèrè, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pa àwọn òfin mi mọ́, kí o sì lépa lati mú jáde wá ati lati ṣe àgbékalẹ̀ ipa ọ̀nà Síónì. 7 Ma ṣe lépa fún ọrọ̀ ṣugbọ́n fún ọgbọ́n; àti, kíyèsíi, àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run ni a ó ṣí fún ọ, àti nígbànáà ni a ó sọ ìwọ di ọlọ́rọ̀. Kíyèsíi, ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìyè àìnípẹ̀kun ni ọlọ́rọ̀. 8 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, àní bí ìwọ ṣe fẹ́ lati ọwọ́ mi bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a ó ṣe é fún ọ; àti, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ yíó jẹ́ ohun èlò fún ṣíṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere ní ìran yìí. 9 Ma ṣe sọ ohunkohun ṣùgbọ́n ironúpìwàdà fún ìran yìí. Pa àwọn òfin mi mọ́, kí o sì ṣe ìrànlọ́wọ́ lati mú iṣẹ́ mi jáde wá, gẹgẹ́bí àwọn òfin mi, ìwọ yíò sì di alábùkúnfún. 10 Kíyèsíi, ìwọ ní ẹ̀bùn kan, tàbí ìwọ yíò ní ẹ̀bùn kan bí ìwọ bá fẹ́ lati ọwọ́ mi nínú ìgbàgbọ́, pẹ̀lú ọkàn òtítọ́, ní gbígbàgbọ́ nínú agbára Jésu Krísti, tàbí nínú agbára mi èyí tí ó nbá ọ sọ̀rọ̀; 11 Nítorí, kíyèsíi, èmi ni ẹnití ó sọ̀rọ̀; èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó ńtàn nínú òkùnkùn, àti pé nípa agbára mi èmi fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí fún ọ. 12 Àti nísisìyí, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ sínú Ẹ̀mì náà èyí tí ó ndarí lati ṣe rere—bẹ́ẹ̀ni, láti ṣe títọ́, láti rìn ní ìtẹríba, láti dájọ́ ní òdodo; èyí sì ni Ẹ̀mí mi. 13 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, èmi yíò fún ọ lára Ẹ̀mí mi, èyí tí yíò fi òye fun iyè inú rẹ, tí yíò sì fi ayọ̀ kún ọkàn rẹ. 14 Àti pé nígbànáà ni ìwọ yíò mọ̀, tàbí nípa èyí ni ìwọ yíò mọ̀, gbogbo ohun èyíkéyìí tí ìwọ bá fẹ́ lati ọ̀dọ̀ mi, èyítí ó níí ṣe pẹ̀lú awọn ohun ti òdodo, nínú ìgbàgbọ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú mi pé ìwọ yíò rí gbà. 15 Kíyèsíi, mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò níláti rò pé a ti pè ọ́ láti wàásù títí tí a ó fi pè ọ́. 16 Dúró fún ìgbà díẹ̀ síi, títí tí ìwọ yíò fi ní ọ̀rọ̀ mi, àpáta mi, ìjọ mi, àti ìhìnrere mi, kí ìwọ lè mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú nípa ẹ̀kọ́ mi. 17 Àti nígbanáà, kíyèsíi, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú rẹ, bẹ́ẹ̀ni, àní gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ rẹ ni a ó ṣe é fún ọ. 18 Pa àwọn òfin mi mọ́; pa ẹnu rẹ mọ́; bẹ ẹ̀bẹ̀ sí Ẹ̀mí mi; 19 Bẹ́ẹ̀ni, fi ara mọ́ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, kí ìwọ lè ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú wá sí ìmọ́lẹ̀ àwọn ohun wọ̃nnì nípa èyí tí a ti sọ—bẹ́ẹ̀ni, ṣíṣe ìtumọ̀ iṣẹ́ mi; ní sùúrù títí ìwọ yíò fi ṣe é yọrí. 20 Kíyèsíi, èyí ni iṣẹ́ rẹ, láti pa àwọn òfin mi mọ́, bẹ́ẹ̀ni, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, iyè àti okun. 21 Máṣe lépa láti kéde ọ̀rọ̀ mi, ṣùgbọ́n lépa lati gba ọ̀rọ̀ mi, àti nígbànáà ni okùn ahọ́n rẹ yíò tú; nígbànáà, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ yíò ní Ẹ̀mí mi àti ọ̀rọ̀ mi, bẹ́ẹ̀ni, agbára Ọlọ́run sí àìṣiyèméjì àwọn ènìyàn. 22 Ṣùgbọ́n nísisìyí pa ẹnu rẹ mọ́; ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ mi èyí tí ó ti jade lọ sí ààrin àwọn ọmọ ènìyàn, àti bákannáà ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ mi èyí tí yíò jade wá ní ààrin àwọn ọmọ ènìyàn, tàbí èyí tí a nṣe ìtumọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ni, títí tí ìwọ yíò fi gba gbogbo ohun tí èmi yíò fi fún àwọn ọmọ ènìyàn ní ìran yìí, àti pé nígbànáà ni a ó fi ohun gbogbo tí ó kù kún un. 23 Kíyèsíi ìwọ ni Hyrum, ọmọ mi; lépa ìjọba Ọlọ́run, ohun gbogbo ni a ó sì fi kún un gẹ́gẹ́bí èyĩnì tí ó tọ́. 24 Kọ́ sí orí àpáta mi, èyí tí ṣe ìhìnrere mi. 25 Má ṣe sẹ́ ẹ̀mí ìfihàn, tàbí ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀, nítorí ègbé ni fún ẹnití ó bá sẹ́ àwọn ohun wọ̀nyí. 26 Nítorínáà, fi pamọ́ sí inú ọkàn rẹ títí di ìgbà náà tí, nínú ọgbọ́n mi, ìwọ yíò fi jáde lọ. 27 Kíyèsíi, èmi nsọ̀rọ̀ sí gbogbo ènìyàn tí ó ní ìfẹ́ inú rere, tí wọn sì ti fi dòjé wọn láti kórè. 28 Kíyèsíi, èmi ni Jésu Krísti, Ọmọ Ọlọ́run. Èmi ni ìyè àti ìmọ́lẹ̀ ayé. 29 Èmi kan náà ni ẹnití ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn tèmi tí àwọn tèmi kò sì gbà mí; 30 Ṣùgbọ́n lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbà mi, àwọn náà ni èmi yíò fi agbára fún láti di ọmọ Ọlọ́run, àní fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nínú orúkọ mi. Amin. ÌPÍN 12 Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Joseph Knight Àgbà, ní Harmony, Pennsylvania, Oṣù Karũn ọdún 1829. Joseph Knight gba àwọn ohun tí Joseph Smith kéde gbọ́ nípa níní àwọn àwo Ìwé Ti Mómónì ní ìkáwọ́ rẹ̀, àti ìṣẹ́ ìtumọ́ tí ó nlọ lọ́wọ́ nígbànáà, òun sì ti fi ọ̀pọ̀ ìgbà ṣe àtìlẹ́hìn fún Joseph Smith àti akọ̀wé rẹ̀, èyí tí ó mú kí ó ṣẽṣe fún wọn láti tẹ̀ síwájú nínú ìtumọ̀. Nítorí ẹ̀bẹ̀ Joseph Knight, Wolíì náà béèrè lọ́wọ́ Olúwa ó sì gba ìfihàn. 1–6, Àwọn òṣìṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà yíò gba èrè ìgbàlà; 7–9, Gbogbo ẹnití ó bá fẹ́ tí wọ́n sí kún ojú òsùnwọ̀n lè ṣe ìrànlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Olúwa. 1 Iṣẹ́ títóbi ati yíyanilẹ́nu kan ti fẹ́ jáde wá ní ààrin àwọn ọmọ ènìyàn. 2 Kíyèsíi, èmi ni Ọlọ́run; tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, èyí tí ó jẹ́ alààyè ati alágbára, ó mú ju idà olójú méjì lọ, láti pín sí ọ̀tọọ̀tọ̀ oríkèé àti mùndùnmúndùn; nítorínáà tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi. 3 Kíyèsíi, oko náà ti funfun tán fún ìkórè, nítorínáà ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti kórè, ẹ jẹ́ kí ó fi dòjé rẹ̀ gún un pẹ̀lú ipá rẹ̀, kí òun sì kórè nígbàtí ọjọ́ sì wà, kí òun baa lè kó o pamọ́ fún ìgbàlà àìlópin ọkàn rẹ̀ nínú ìjọba Ọlọ́run. 4 Bẹ́ẹ̀ni, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dòjé rẹ̀ tí ó sì kórè, ẹni náà ni Ọlọ́run pè. 5 Nítorínáà, bí ìwọ bá béèrè ní ọwọ́ mi ìwọ yíò rí gbà; bí ìwọ bá kan ìlẹ̀kùn a ó ṣí i fún ọ. 6 Nísisìyí, bí ìwọ ti béèrè, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pa àwọn òfin mi mọ́, kí o sì lépa lati mú jáde wá ati lati ṣe àgbékalẹ̀ ipa ọ̀nà Síónì. 7 Kíyèsíi, èmi ńba ọ sọ̀rọ̀, àti bákannáà sí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ láti mú iṣẹ́ yìí jade wá àti láti ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀. 8 Àti pé ẹnikẹ́ni kò lè ṣe ìrànwọ́ nínú iṣẹ́ yìí bí kò ṣe pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì kún fún ìfẹ́, pẹ̀lú níní ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, pẹ̀lú wíwà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì nínú ohun gbogbo, èyíkéyìí tí a lè fi sí abẹ́ ìtọ́jú rẹ̀. 9 Kíyèsíi, èmi ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé, tí ó ńsọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nítorínáà fi etí sí ọ̀rọ̀ mi pẹ̀lú agbára rẹ, nígbànáà ìwọ ni a pè. Amin. ÌPÍN 13 Àyọkúrò láti inú ìwé ìtàn ti Joseph Smith tí ó ṣe àpéjúwe ìlànà ìfinijoyè ti Wòlíì náà àti Oliver Cowdery sí oyè àlufáà ti Aarónì ní itòsí Harmony, Pennsylvania, ọjọ́ kẹ̃dógún Oṣù karũn 1829. Ìfinijoyè náà ni a ṣe lati ọwọ́ angẹ́lì kan tí ó kéde ara rẹ̀ bíi Jòhánnù, ẹ̀ni kannáà tí a pè ní Jòhánnù Onítẹ̀bọmi nínú Májẹ̀mu Titun. Angẹ́lì náà ṣe àlàyé pé òun nṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Péterù, Jákọ́bù, àti Johannù, àwọn Àpostélì ìgbàanì, tí wọ́n ní àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà gíga, èyítí a pè ní Òyè àlùfáà ti Melkizedekì. Ìlérì náà ni a fi fún Joseph àti Oliver pé nígbàtí àkókò bá tó òyè àlufáà gíga yìí yíó di fífi lé wọn lórí. (Wo ìpín 27:7–8, 12.) Àwọn kọ́kọ́rọ́ àti agbára oyè àlùfáà ti Aarónì ni a fi lélẹ̀. 1 Ní orí yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi, ní orúkọ Mèssíà mo fi oyè àlùfáà ti Aarónì fũn yín, èyí tí ó ní kọ́kọ́rọ́ ti ìṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì, àti ti ìhìnrere ironúpìwàdà, àti ti ìrìbọmi nípa rírì bọmi fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀; àti pé a kì yíò mú èyí kúrò ní ilé ayé mọ́ láí, títí tí àwọn ọmọ Léfì yíò fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan síi ẹbọ-ọrẹ kan sí Olúwa nínú òdodo. ÌPÍN 14 Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wolíì Joseph Smith sí David Whitmer, ní Fayette, New York, Oṣù Kẹfà 1829. Àwọn mọ̀lẹ́bí Whitmer ti ní ìfẹ́ púpọ̀ sí iṣẹ́ ìtumọ̀ Ìwé Ti Mọ́mọ́nì. Wòlíì náà ti fi ibùgbé rẹ̀ kalẹ̀ sí ilé Peter Whitmer Àgbà, níbẹ̀ ni ó ngbé títí tí iṣẹ́ ìtumọ̀ ìwé náà fi dé ìparí àti tí wọ́n fi gba àṣẹ láti tẹ ìwé tí ó nbọ̀ náà sí ìta. Mẹ́ta nínú àwọn ọmọ Whitmer, tí ọkọ̀ọ̀kan nínú wọn ti gba ẹ̀rí nípa bí ìwé náà ṣe jẹ́ òtítọ́ tó wá wòye bí ó ṣe kàn wọ́n tó láti mọ́ ojúṣe tí wọ́n ní kárakára gẹ́gẹ́bí olúkúlùkù. Ìfihàn yìí àti méjì tí yíò tẹ̀lé e (Ìpín Kẹ̃dogún àti ẹkẹrìndínlógún) ni a gbà ní ìdáhùn sí ìbéèrè kan nípa lílo Urimù àti Thummimù. David Whitmer di ọ̀kan nínú Àwọn Ẹlẹ́rìí Mẹ́ta Ìwé Ti Mọ́mọ́nì. 1–6, Àwọn òṣìṣẹ́ nínú ọgbà ajarà yíò gba èrè ìgbàlà; 7–8, Iyè àìnípẹ̀kun ni ó ga jùlọ nínú àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run. 9–11, Krísti dá ọ̀run àti ayé. 1 Iṣẹ́ títóbi ati yíyanilẹ́nu kan fẹ́ jáde wá sí àwọn ọmọ ènìyàn. 2 Kíyèsíi, èmi ni Ọlọ́run; tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, èyí tí ó jẹ́ alààyè àti alágbára, ó mú ju idà olójú méjì lọ láti pín sí ọ̀tọọ̀tọ̀ oríkèé àti mùndùnmúndùn; nítorínáà tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi. 3 Kíyèsíi, oko náà ti funfun tán fún ìkórè, nítorínáà ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti kórè, ẹ jẹ́ kí ó fi dòjé rẹ̀ pẹ̀lú ipá rẹ̀, kí ó sì kórè nígbàtí ọjọ́ sì wà, kí ó le kó ìgbàlà àìlópin pamọ́ fún ọkàn rẹ̀ nínú ìjọba Ọlọ́run. 4 Bẹ́ẹ̀ni, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dòjé rẹ̀ tí ó sì kórè, òun kannáà ni Ọlọ́run pè. 5 Nítorínáà, bí ìwọ bá béèrè ní ọwọ́ mi, ìwọ yíò rí gbà; bí ìwọ bá kan ìlẹ̀kùn a ó ṣí i fún ọ. 6 Lépa láti mú jade wá àti láti ṣe àgbékalẹ̀ Síónì mi. Pa àwọn òfin mi mọ́ nínú ohun gbogbo. 7 Àti pé, bí ìwọ bá pa àwọn òfin mi mọ́ tí o sì fi orí tìí dé òpin ìwọ yíò ní ìyè ayérayé, ẹ̀bùn èyí tí ó ga jùlọ nínú àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run. 8 Yíò sí ṣe, pé bí ìwọ bá béèrè lọ́wọ̀ Bàbá ní orúkọ mi, pẹ̀lú ìgbágbọ́, ìwọ yíò gba Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí ó ńfun ni ní ọ̀rọ̀ sísọ, kí ìwọ kí ó lè dúró gẹ́gẹ́bí ẹlẹ́rìí àwọn ohun tí ìwọ yíò rí àti tí ìwọ yíò gbọ́, àti bákannáà pé kí ìwọ kí ó lè kéde ironúpìwàdà sí ìran yìí. 9 Kíyèsíi, èmi ni Jésu Krísti, Ọmọ Ọlọ́run alààyè, ẹnití ó dá àwọn ọ̀run àti ayé, ìmọ́lẹ̀ tí kò lè fara sin nínú òkùnkùn; 10 Ati nísisìyí, èmi gbọ́dọ̀ mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi jade wá láti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí sí ilé Israeli. 11 Àti kíyèsíi, ìwọ ni Dáfídì, ìwọ̀ ni a sì pè láti ṣe ìrànlọ́wọ́; èyítí bí ìwọ bá ṣe ohun náà, bí o bá sì jẹ́ olõtọ́, a ó bùkún fún ọ ní ti ẹ̀mí àti ní ti ara, púpọ̀ ni èrè rẹ yíò sì jẹ́. Amín. ÌPÍN 15 Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí John Whitmer, ní Fayette, New York, Oṣù Kẹfà ọdún 1829. (wo àkọlé sí ìpín 14). Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ohun tí ó kanni gbọ̀ngbọ̀n ati àtẹ̀mọ́ ti ara ẹni nítorí pé Olúwa sọ ohun tí ó jẹ́ mímọ̀ sí John Whitmer nìkan àti òun Tìkára Rẹ̀. John Whitmer di ọ̀kan nínú Àwọn Ẹlérìí Mẹ́jọ sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì lẹ́hìn náà. 1–2, Apá Olúwa wà kárí gbogbo ilẹ̀ ayé; 3–6, Láti wàásù ìhìnrere àti láti gba àwọn ọkàn là ni ohun tí ó níye lórí jùlọ. 1 Fetísílẹ̀, ìranṣẹ́ mi Jòhánnù, kí o sì tẹ́tísí àwọn ọ̀rọ̀ Jésu Krísti, Olúwa rẹ àti Olùràpadà rẹ. 2 Nítorí kíyèsíi, èmi sọ̀rọ̀ sí ọ pẹ̀lú ohùn mímú àti pẹ̀lú agbára, nítorí apá mi wà lórí gbogbo ilẹ̀ ayé. 3 Àti pé èmi yíò sọ àwọn ohun kan fún ọ èyítí èniyàn kankan kò mọ̀ àfi èmi àti ìwọ nìkan— 4 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ìwọ ti fẹ́ mọ̀ lati ọ̀dọ̀ mi èyíinì tí yíó ní iye lórí jùlọ sí ọ. 5 Kíyèsíi, ìbùkún ni fún ọ nítorí ohun yí, àti fún sísọ àwọn ọ̀rọ̀ mi èyí tí mo fi fún ọ gẹ́gẹ́bí àwọn òfin mi. 6 Àti nísisìyí, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé ohun kan tí yíó níye lórí jùlọ fún ọ ni lati kéde ìrònúpìwàdà fún àwọn ènìyàn yìí, kí ìwọ baà lè mú àwọn ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí ìwọ ó lè sínmi pẹ̀lú wọn ní ìjọba Bàbá mi. Amin. ÌPÍN 16 Ìfihàn tí a fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Peter Whitmer Kékeré, ní Fayette, New York, Oṣu Kẹfà 1829. (wo àkọlé sí ìpín 14). Peter Whitmer Kekere di ọ̀kan nínú Àwọn Ẹlérìí Mẹ́jọ fún ìwé Ti Mọ́mọ́nì lẹ́hìn náà. 1–2, Apá Olúwa wà kárí gbogbo ilẹ̀ ayé; 3–6, Láti wàásù ìhìnrere àti láti gba àwọn ọkàn là ni ohun tí ó níye lórí jùlọ. 1 Fetísílẹ̀, ìránṣẹ́ mi Peter, kí o sì tẹ́tísí àwọn ọ̀rọ̀ ti Jésu Krísti, Olúwa rẹ àti Olùràpadà rẹ. 2 Nítorí kíyèsíi, èmi sọ̀rọ̀ sí ọ pẹ̀lú ohùn mímú àti pẹ̀lú agbára, nítorí apá mi wà lórí gbogbo ilẹ̀ ayé. 3 Àti pé èmi yíò sọ àwọn nkan fún ọ tí èniyàn kankan kò mọ̀ àfi èmi àti ìwọ nìkan— 4 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ìwọ ti fẹ́ mọ̀ lati ọ̀dọ̀ mi èyíinì tí yíó ní iye lórí jùlọ sí ọ. 5 Kíyèsíi, ìbùkún ni fún ọ nítorí ohun yìí, àti fún sísọ àwọn ọ̀rọ̀ mi èyí tí mo ti fi fún ọ gẹ́gẹ́bí àwọn òfin mi. 6 Àti nísisìyí, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé ohun tí yíó níye lórí fún ọ jùlọ ni lati kéde ironúpìwàdà sí àwọn ènìyàn yìí, kí ìwọ baà lè mú àwọn ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí ìwọ baà lè sinmi pẹ̀lú wọn nínú ìjọba Bàbá mi. Amin. ÌPÍN 17 Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Oliver Cowdery, David Whitmer, àti Martin Harris ní Fayette, New York, Oṣù Kẹfà 1829, síwájú kí wọ́n ó tó wo àwọn àwo tí a fín nínú èyí tí àkọsílẹ̀ Ìwé Ti Mọ́mọ́nì wà. Joseph àti akọ̀wé rẹ̀, Oliver Cowdery ti kọ́ ẹ̀kọ́ lati inú ìtumọ̀ àwọn àwo Ìwé Ti Mọ́mọ́nì pé àwọn Ẹlérìí pàtàkì mẹ́ta ni a ó yàn (wo Ìwé Étérì 5:2–4; Ìwé Néfì 11:3; 27:12). Oliver Cowdery, David Whitmer, àti Martin Harris ti ní ìwúrí nípa fífẹ́ nínú ìmísí láti jẹ́ Ẹlérìí pàtàkì mẹ́ta náà. Wòlíì náà beerè lọ́wọ́ Olúwa, ìfihàn yìí ni a sì fi fúnni ní ìdáhùn nípasẹ̀ Urímù àti Túmmímù. 1–4, Nípa ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlérìí Mẹ́ta yíò rí àwọn àwo náà ati àwọn ohun mímọ́ mìíràn; 5–9, Krísti jẹ́rìí sí jíjẹ́ àtọ̀runwá Ìwé Ti Mọ́mọ́nì. 1 Kíyèsíi, mo wí fún yín, pé ẹ gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi, èyí tí ó jẹ́ pé bí o bá ṣe é pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrèdí ti ọkàn, ẹ̀yin yíò rí àwọn àwo náà, àti àwo ìgbàyà bákannáà, idà ti Lábánì, Urímù àti Túmmímù, èyítí a kó fún arákùnrin Járedì ní orí òkè, nígbàtí ó bá Olúwa sọ̀rọ̀ ní ojú korojú, àti àwọn ìdarí ìyanu èyí tí a fún Léhì nígbàtí ó wà nínú aginjù, ní ààlà Òkun Pupa. 2 Àti pé nípa ìgbàgbọ́ yín ni ẹ̀yin yíò lè rí wọn, àní nípa ìgbàgbọ́ náà èyí tí àwọn Wòlíì ìgbàanì ní. 3 Àti pé lẹ́hìn tí ẹ bá ti ní ìgbàgbọ́, tí ẹ sì ti rí wọn pẹ̀lú ojú yín, ẹ̀yin yíò jẹ́rìí sí wọn, nípa agbára Ọlọ́run; 4 Àti pé èyí ni ẹ̀yin yíò ṣe kí ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, Kékeré, má baà di píparun, kí èmi baà lè mú àwọn èrò òdodo mi ṣẹ sí àwọn ọmọ ènìyàn nínú iṣẹ́ yìí. 5 Àti pé ẹ̀yin yíò jẹ́rìí pé ẹ̀yin ti rí àwọn ohun wọ̀nyí, àní bí ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, Kekere, náà ṣe rí wọn; nítorí nípa agbára mi ni òun fi rí wọn, àti nítorípé ó ní ìgbàgbọ́. 6 Àti pé òun ti túmọ̀ ìwé náà, àní abala èyí tí mo paláṣẹ fún un, àti pé bí Olúwa àti Ọlọ́run yín ṣe wà láàyè ó jẹ́ òtítọ́. 7 Nítorínáà, ẹ̀yin ti gba agbára kan náà, àti ìgbàgbọ́ kan náà, àti ẹ̀bùn kan náà gẹ́gẹ́bí ti òun. 8 Àti pé bí ẹ̀yin bá ṣe àwọn òfin mi ìkẹ́hìn yìí, èyí ti mo ti fi fún yín, àwọn ẹnu ọ̀nà ọ̀run apáàdi kì yíò lè borí yín; nítorípé oore ọ̀fẹ́ mi tó fún yín, a ó sì gbé yín sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn. 9 Àti pé èmi, Jésu Krísti, Olúwa yín àti Ọlọ́run yín ti sọ ọ́ fún yín, kí èmi baà lè mú àwọn èrò òdodo mi ṣẹ sí àwọn ọmọ ènìyàn. Amin. ÌPÍN 18 Ìfihàn sí Wòlíì Joseph Smith, Oliver Cowdery, àti David Whitmer, tí a fi fúnni ní Fayette, New York, Oṣú Kẹfà 1829. Gẹ́gẹ́bí Wòlíì ti sọ, ìfihàn yìí sọọ́ di mímọ̀ “ìpè ti àwọn àpóstélì méjìlá ní àwọn ọjọ́ tí ó gbẹ̀hìn wọ̀nyí, àti bákannáà àwọn òfin tí ó ní ṣe sí mímú Ìjọ dàgbà.” 1–5, Àwọn ìwé mímọ́ fi ọ̀nà tí a lè fi gbé ìjọ kalẹ̀ hàn, 6–8, Ayé ńbàjẹ́ síi nínú àìṣedéédé; 9–16, Àwọn ọkàn ṣe iyebíye púpọ̀; 17–25, Láti jẹ èrè ìgbàlà, àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ gba orúkọ Krísti sí orí wọn; 26–36, Pípè àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn Méjìlá ni a fi hàn; 37–39, Oliver Cowdery àti David Whitmer yíò ṣe àwárí àwọn Méjìlá; 40–47, Láti jẹ èrè ìgbàlà, àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà, kí a sì rì wọ́n bọmi, kí wọ́n ó sì pa àwọn òfin mọ́. 1 Nísisìyìí, kíyèsíi, nítorí ohun eyítí ìwọ, ìransẹ́ mi Oliver Cowdery, ti ní ìfẹ́ lati mọ̀ nípasẹ̀ mi, mo fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún ọ. 2 Kíyèsíi, mo ti fi hàn fún ọ, nípa Ẹ̀mí mi nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹrẹ, pé awọn ohun tí ìwọ ti kọ jẹ́ òtítọ́; nítorínáà ìwọ mọ̀ pé wọ́n jẹ́ òtítọ́. 3 Àti pé bí ìwọ bá mọ̀ pé wọ́n jẹ́ òtítọ́, kíyèsíi, èmi fi òfin kan fún ọ, pé kí ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ohun tí a ti kọ. 4 Nítorí nínú wọn ni a kọ ohun gbogbo sí nípa ìpìlẹ̀ ìjọ mi, ìhìnrere mi, àti àpáta mi. 5 Nítorínáà, bí ìwọ yíò bá kọ́ ìjọ mi lé orí ìpìlẹ̀ ìhìnrere mi àti àpáta mi, àwọn ẹnu ọ̀nà ọ̀run àpãdì kì yíò lè borí rẹ. 6 Kíyèsíi, ayé ńbàjẹ́ nínú àìṣedéédé; ó sì di gbígbọdọ̀ ṣe pé kí àwọn ọmọ ènìyàn rú sókè sí ironúpìwàdà, àti àwọn Kèfèrí àti bákannáà ìdílé Isráelì. 7 Nítorínáà, bí a ṣe ti rì ọ́ bọmi láti ọwọ́ ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, Kekeré, gẹgẹbí èyíinì tí mo paláṣẹ fún un, òun ti ṣe ohun tí mo pa láṣẹ fún un. 8 Àti nísisìyí, kí ẹnu máṣe yà ọ pé mo ti pè é fún ètò tèmi, ètò èyítí ó jẹ́ mímọ̀ nínú mi; nítorí èyí, bí òun yíò bá jẹ́ aláìṣèmẹ́lẹ́ ní pípa àwọn òfin mi mọ́ òun yíò di alábùkún fún sí ìyè ayérayé; àti pé orúkọ rẹ̀ ni Joseph. 9 Àti nísisìyí, Oliver Cowdery, èmi bá ọ sọ̀rọ̀, àti bákannáà sí David Whitmer, nípa ọ̀na àṣẹ; nítorí, kíyèsíi, mo paáláṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbigbogbo láti ronúpìwàdà, àti pé mo wí fún yín, àní bíi sí Paul Àposteli mi, nítorí a pè yín àní pẹ̀lú ìpè kan náà pẹ̀lú èyítí a fi pè òun. 10 Rántí, àwọn ọkàn ṣe iyebíye púpọ̀ níwájú Ọlọ́run; 11 Nítorí, kíyèsíi, Olúwa Olùràpadà rẹ jìyà ikú nínú ẹran ara; nítorínáà òun jìyà fún ìrora gbogbo ènìyàn, kí gbogbo ènìyàn lè ronúpìwàdà kí wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. 12 Àti pé òun ti tún jí dìde kúrò nínú òkú, kí òun lè mú gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, lórí ìpinnu ironúpìwàdà. 13 Àti pé báwo ni ayọ̀ rẹ̀ ti pọ̀ tó lórí ọkàn tí ó ronúpìwàdà! 14 Nítorínáà, a pè yín láti kígbe ironúpìwàdà sí àwọn ènìyàn yìí. 15 Bí ó bá sì rí bẹ́ẹ̀ pé ẹ̀yin ṣe làálàá ní gbogbo ọjọ́ ayé yín ní kíkígbe ironúpìwàdà sí àwọn ènìyan yìí, tí ẹ̀yin sì mú, bí ó ṣe ọkàn kan péré wá sí ọ̀dọ̀ mi, báwo ni ayọ̀ yín yíò ṣe pọ̀ tó pẹ̀lú rẹ̀ ní ìjọba Bàbá mi! 16 Àti nísisìyí, bí ayọ̀ yín yíò bá pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan tí ẹ̀yin mú wá sí ọ̀dọ̀ mi sínú ìjọba Bàbá mi, báwo ni ayọ̀ yín yíò ṣe pọ̀ tó bí ẹ̀yin bá lè mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ mi! 17 Kíyèsíi, ẹ̀yin ní ìhìnrere mi níwájú yín, àti àpáta mi, àti ìgbàlà mi. 18 Ẹ béèrè ní ọwọ́ Bàbá ní orúkọ mi pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ní gbígbàgbọ́ pé ẹ̀yin yío rí gbà, ẹ̀yin yíò sì ní Ẹ̀mí Mímọ́, èyítí ó nfi ohun gbogbo hàn tí ó wúlò fún àwọn ọmọ ènìyàn. 19 Àti pé bí ẹ̀yin kò bá ní ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, ẹ̀yin kò lè ṣe ohunkóhun. 20 Ẹ máṣe ja ìjàdù pẹ̀lú ìjọ kankan, àfi bí ó bá jẹ́ ìjọ ti èṣù. 21 Ẹ gba orúkọ Jésu sí orí yín, kí ẹ sì sọ òtítọ́ pẹ̀lú ìronújinlẹ̀. 22 Àti pé iye àwọn tí wọ́n bá ronúpìwàdà tí a sì rìbọmi ní orúkọ mi, èyí tíí ṣe Jésu Krísti, àti ti wọ́n forítì í dé òpin, àwọn kannáà ni a ó gbàlà. 23 Kíyèsíi, Jésu Krísti ni orúkọ tí Bàbá fi fúnni, àti pé kò sí orúkọ míràn tí a fi fúnni nípa èyí tí ènìyàn lè rí ìgbàlà. 24 Nítorínáà, gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ gba orúkọ náà sí orí ara wọn èyítí Bàbá fi fúnni, nítorí nínú orúkọ yìí ni a ó pè wọ́n ní ọjọ́ ìkẹhìn; 25 Nítorínáà, bí wọn kò bá mọ orúkọ èyí tí a fi pè wọ́n, wọn kì yíò lè ní ààyè nínú ìjọba Bàbá mi. 26 Àti nísisìyí, kíyèsíi, àwọn kan wà tí a pè láti kéde ìhìnrere mi, sí àwọn Kèfèrí àti sí àwọn Júù. 27 Bẹ́ẹ̀ni, àní àwọn méjìlá; àti pé àwọn Méjìlá náà yíó jẹ́ ọmọ ẹ̀hìn mi, wọn yíò sì gba orúkọ mi sí orí wọn; àti pé àwọn Méjìlá náà ni àwọn tí yíò ní ìfẹ́ láti gba orúkọ mi sí orí wọn pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrò ọkàn. 28 Àti pé bí wọ́n bá ní ìfẹ́ láti gba orúkọ mi sí orí wọn pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrò ọkàn, a pè wọ́n láti lọ sí gbogbo ayé láti wàásù ìhìnrere mi sí gbogbo ẹ̀dá. 29 Àti pé àwọn ni àwọn náà tí a ti yàn láti ọwọ́ mi láti rìbọmi ní orúkọ mi, gẹ́gẹ́bí èyítí a ti kọ; 30 Àti pé ìwọ ní èyí tí a ti kọ níwájú rẹ; nítori èyí, o gbọ́dọ̀ ṣe e gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti kọ. 31 Àti nísisìyí èmi báa yín sọ̀rọ̀, ẹ̀yin Méjìlá—Ẹ kíyèsíi, oore ọ̀fẹ́ mi tó fún yin; ẹ gbọ́dọ̀ rìn ní títọ́ níwájú mi kí ẹ sì máṣe dẹ́ṣẹ̀. 32 Àti, kíyèsíi, ẹ̀yin ni awọn náà tí a yàn láti ọwọ́ mi lati yan àwọn àlùfáà àti àwọn olùkọ́ni; lati kéde ìhìnrere mi, gẹ́gẹ́bí agbára Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó wà nínú yin, àti gẹ́gẹ́bí àwọn ìpè àti àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn; 33 Àti pé èmi, Jésu Krísti, Olúwa rẹ àti Ọlọ́run rẹ, ti sọ̀ ọ́. 34 Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kìí ṣe lati ọ̀dọ̀ awọn ènìyàn tàbí láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan; ṣùgbọ́n lati ọ̀dọ̀ mi; nítorí-èyí, ẹ̀yin yíò jẹ́rìí síi pé wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ mi, kìí sìí ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn. 35 Nítorí ohùn ti èmi ni èyítí ó sọ wọ́n jade fún yín; nítorí a fi wọ́n fúnni nípa Ẹ̀mí mi síi yín, àti nípa agbára mi ẹ̀yin le kà wọ́n, ẹ̀nìkan sí ẹlòmíràn; àti pé bíkòṣe nípa agbára mi ẹ̀yin kò lè ní wọn. 36 Nítorí-èyí, ẹ̀yin le jẹ́rìí pé ẹ ti gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin sì mọ àwọn ọ̀rọ̀ mi. 37 Àti nísisìyí, kíyèsíi, èmi fi fún ọ, Oliver Cowdery, àti bákannáà fún David Whitmer, pé ẹ̀yin yíò ṣe àwárí àwọn Méjìlá, tí wọn yíò ní ìfẹ́ inú èyí tí mo ti sọ nípa rẹ̀; 38 Àti nípa àwọn ìfẹ́ inú wọn àti àwọn iṣẹ́ wọn ni ẹ̀yin yíò mọ̀ wọ́n. 39 Àti pé nígbàtí ẹ̀yin bá ti rí wọn ẹ̀yin yíò fi àwọn nkan wọ̀nyí hàn sí wọn. 40 Ẹ̀yin yíò sì wólẹ̀, ẹ ó sí bu ọlá fún Bàbá ní orúkọ mi. 41 Àti pé ẹ̀yin gbọ́dọ̀ wàásù fún ayé, ní sísọ pé: Ẹ gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà kí a sì ṣe ìrìbọmi fún yín, ní orúkọ Jésu Krísti; 42 Nítorí gbogbo ènìyàn ni wọ́n gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà kí wọ́n sì sì rì wọ́n bọmi, kìí sìí ṣe ọkùnrin nìkan, ṣùgbọ́n àti àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé tí wọ́n ti dé awọn ọdún ìjíhìn. 43 Àti nísisìyí, lẹ́hìn tí ẹ bá ti gba èyí, ẹ̀yin gbọ́dọ̀ pa àwọn òfin mi mọ́ nínú ohun gbogbo. 44 Àti pé láti ọwọ́ yín èmi yíò ṣe iṣẹ́ yíyanilẹ́nu kan láàrin àwọn ọmọ ènìyàn, sí fífi dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ lójú ní ti awọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí wọ́n ó lè wá sí ironúpìwàdà, àti pé kí wọn ó lè wá sí ìjọba Bàbá mi. 45 Nítorí-èyí, àwọn ìbùkún tí èmi fi fún yín ju ohun gbogbo lọ. 46 Àti pé lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti gba èyí, bí ẹ̀yin kò bá pa àwọn òfin mi mọ́, a kì yíò gbà yín là nínú ìjọba Bàbá mi. 47 Kíyèsíi, èmi, Jésù Krístì, Olúwa rẹ àti Ọlọ́run rẹ, àti Olùràpadà rẹ, nípa agbára Ẹ̀mí mi ni mo fi sọ ọ́. Amin. ÌPÍN 19 Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Manchester, New York, ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ ìgbà ooru 1829. Nínú ìtàn rẹ̀, Wòlíì náà ṣe àfihàn rẹ̀ bíi “òfin ti Ọlọ́run tí kìí sìí ṣe ti ènìyàn, sí Martin Harris, tí a fi fúnni láti ọ̀dọ̀ ẹni náà tí ó jẹ́ Ayérayé.” 1–3, Krístì ní gbogbo agbára; 4–5, Gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà tàbí kí wọ́n ó jìyà; 6–12, Ìbáwí àìlópin jẹ́ ìbáwí ti Ọlọ́run; 13–20, Krístì jìyà fún gbogbo ènìyàn, pé kí wọn ó má baà jìyà bí wọn bá lè ronúpìwàdà; 21–28, Wàásù ìhìnrere ironúpìwàdà; 29–41, Kéde àwọn ìhìn ayọ̀. 1 Èmi ni Álfà àti Òmégà, Krístì Olúwa; bẹ́ẹ̀ni, àní èmi ni, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin, Olùràpadà aráyé. 2 Èmi, lẹ́hìn tí mo ti ṣetán tí mo sì parí ìfẹ́ inú ẹni náà tí èmi í ṣe tirẹ̀, àní Bàbá náà, nípa èmi—tí mo ti ṣe èyí kí èmi ó baà lè mú ohun gbogbo wá sábẹ́ àkóso èmi tìkara mi— 3 Níní gbogbo agbára ní ìkáwọ́, àní láti pa Sátánì àti awọn iṣẹ́ rẹ̀ run ní òpin ayé, àti ní ọjọ́ ìdájọ́ nlá tí ó kẹ́hìn, èyí tí èmi yíò ṣe ní orí àwọn olùgbé ibẹ̀, ní dídájọ́ olukúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ rẹ̀ àti awọn ohun èyí tí ó ti ṣe. 4 Àti pé dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà tàbí kí wọn ó jìyà, nítorí èmi, Ọlọ́run, mo jẹ́ àìnípẹ̀kun. 5 Nítorí-èyí, èmi kò pa àwọn ìdájọ́ èyítí èmi yíó ṣe rẹ́, ṣùgbọ́n àwọn ègbé yíò wá síwájú, ẹkún, ìpohùnréré ẹkún, àti ìpahínkeke, bẹ́ẹ̀ni, sí àwọn tí wọ́n bá wà ní ọwọ́ òsì mi. 6 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a kò kọọ́ pé kò ní sí òpin sí oró yìí, ṣùgbọ́n a kọọ́ pé oró àìnípẹ̀kun. 7 Lẹ́ẹ̀kansíi, a kọọ́ pé ìdálẹ́bi ayérayé; nítorínáà ó hàn gbangba ju àwọn ẹsẹ míràn lọ, pé kí èyí lè ṣiṣẹ́ lórí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn, ní àpapọ̀ fún ògo orúkọ mi. 8 Nítorí-èyí, èmi yíò ṣe àlàyé ohun ìjìnlẹ̀ yìí fún ọ, nítorí ó yẹ kí ìwọ mọ̀ àní gẹ́gẹ́bí àwọn àpostélì mi. 9 Èmi nsọ̀rọ̀ sí ẹ̀yin tí a yàn nípa ohun yìí, àní bíi ẹnìkan, kí ẹ̀yin baà lè wọ inú ìsinmi mi. 10 Nítorí, kíyèsíi, ohun ìjìnlẹ̀ ti ìwà-bí-Ọlọ́run, báwo ni ó ṣe tóbi tó! Nítorí, kíyèsíi, èmi jẹ́ àìnípẹ̀kun, àti pé ìbáwí èyí tí a fi fúnni láti ọwọ́ mi jẹ́ àìlópin, nítorí Àìnípẹ̀kun ni orúkọ mi. Nítorí-èyí— 11 Ìjìyà ayérayé jẹ́ ìjìyà ti Ọlọ́run. 12 Ìjìyà àìlópin jẹ́ ìjìyà ti Ọlọ́run. 13 Nitorí-èyí, mo pàṣẹ fún ọ lati ronúpìwàdà, kí o sì pa àwọn òfin mọ́ èyítí ìwọ ti gbà láti ọwọ́ ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, Kekere, ní orúkọ mi. 14 Àti pé nípa agbára mi títóbi jùlọ ni ìwọ fi gbà wọ́n. 15 Nísisìyí mo pàṣẹ fún ọ lati ronúpìwàdà—ronúpàwàdà, bí bẹ́ẹ̀kọ́ èmi yíò nà ọ́ pẹ̀lú ọ̀gọ ẹnu mi, àti pẹ̀lù ìrunú mi, àti pẹ̀lú ìbínu mi, àti pé àwọn ìrora rẹ yíò dunni jọjọ—bí yíò ṣe dunni tó ìwọ kò mọ̀, bí yíò ṣe rẹwà tó ìwọ kò mọ̀, bẹ́ẹ̀ni, bí yíò ṣe nira láti faradà tó ìwọ kò mọ̀. 16 Nítorí kíyèsíi, èmi, Ọlọ́run, ti jìya àwọn ohun wọ̀nyí fún gbogbo èniyàn, pé kí àwọn má baà jìyà bí wọ́n bá lè ronúpìwàdà; 17 Ṣùgbọ́n bí wọ́n kò bá ní ronúpìwàdà wọ́n gbọ́dọ̀ jìyà àní bí ti èmi; 18 Ìjìyà tí èyítí ó mú èmi tìkara mi, àní Ọlọ́run, tí ó tóbi jù ohun gbogbo lọ, láti gbọ̀n-rìrì nítorí ìrora, àti lati ṣẹ̀jẹ̀ nínú gbogbo ihò ara, àti láti jìyà ní ara àti ẹ̀mí—àti lati fẹ́ pé kí èmi máṣe mu nínú aago kíkorò náà, tí èmi sì fàsẹ́hìn— 19 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ògo ni fún Bàbá, àti pé èmi kópa mo sì ṣe àṣeparí àwọn ìmúrasílẹ̀ mi fún àwọn ọmọ ènìyàn. 20 Nítorí-èyí, mo pàṣẹ fún ọ lẹ́ẹ̀kansíi lati ronúpìwàdà, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yíò rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú agbára mi títóbi jùlọ; àti pé kí ìwọ jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìwọ yíó jìyà àwọn ìbáwí èyítí èmi ti sọ, nínú èyíti ó jẹ́ kékeré jùlọ, bẹ́ẹ̀ni, àní nínú ìwọ̀n tí ó kéré jù ni ìwọ ti tọ́ wò ní àkókò tí mo gba ẹ̀mí mi kúrò. 21 Àti pé mo pàṣẹ fún ọ pé kí o má ṣe wàásù ohun míràn ṣùgbọ́n ìrònúpìwàdà, àti kí o máṣe fi àwọn ohun wọ̀nyí hàn fún ayé títí yíò fi jẹ́ ọgbọ́n nínú mi. 22 Nitorí wọn kò tíi lè gba ẹran báyìí, ṣùgbọ́n wàrà ni wọ́n gbọdọ̀ gbà; nítorí-èyí, wọn kò gbọdọ̀ mọ àwọn ohun wọnyìí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ wọ́n yío ṣègbé. 23 Kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi, kí o sì tẹ́tísí àwọn ọ̀rọ̀ mi; rìn nínú ìwà pẹ̀lẹ́ ti Ẹ̀mí mi, ìwọ yíò sì ní àlàáfíà nínú mi. 24 Èmi ni Jésù Krístì; Èmi wá nípa ìfẹ́ ti Bàbá, Èmi sì nṣe ìfẹ́ rẹ̀. 25 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ; tàbí kí o lépa ẹ̀mí ẹnìkéjì rẹ. 26 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ohun ìní rẹ, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi òmìnira jọ̀wọ́ rẹ̀ fún iṣẹ́ títẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, èyí tí ó ní òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú— 27 Èyítí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ mi sí àwọn Kèfèrí, pé láìpẹ́ kí ó le lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Júù, tí àwọn ará Lámánì jẹ́ ìyókù wọn, pé kí wọn ó le gba ìhìnrere náà gbọ́, ati kí wọ́n ó sì má baà tún fi ojú sọ́na fún Messia kan lati wá ẹni tí ó ti wá tẹ́lẹ̀. 28 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi pàṣẹ fún ọ pé kí ìwọ ó máa gbàdúrà ní gbígbé ohùn sókè àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ nínú ọkàn rẹ; bẹ́ẹ̀ni, níwájú àwọn ènìyàn àti ní ìkọkọ̀, ní gbangba àti nínú ìyẹ́wù. 29 Àti pé ìwọ yíò kéde àwọn ìrohìn ayọ̀, bẹ́ẹ̀ni, kéde rẹ̀ ní orí àwọn òkè, àti ní gbogbo ibi gíga, àti lààrin àwọn ènìyàn gbogbo tí a ó gbà ọ́ láàyè láti rí. 30 Àti pé ìwọ yíò ṣe é pẹ̀lú gbogbo ìwà ìrẹ̀lẹ̀, níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú mi, láì pẹ̀gàn àwọn apẹ̀gàn. 31 Àti pé nípa àwọn ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ ni ìwọ kí yíò sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ yío kéde ironúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà, àti ìdárìjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa ìrìbọmi, àti nípa iná, bẹ́ẹ̀ni, àní Ẹ̀mí Mímọ́. 32 Kíyèsíi, èyí jẹ́ títóbi ati tí ìkẹhìn nínú òfin tí èmi yíò fi fún ọ nípa ohun yìí; nítorí èyí yíò tó fún irìn òòjọ́ rẹ, àní títí dé òpin ọjọ́ ayé rẹ. 33 Àti pé òṣì ni ìwọ yíò gbà bí ìwọ kò bá ka àwọn ìmọràn wọ̀nyìí sí, bẹ́ẹ̀ni, àní ìparun tìrẹ àti ohun ìní rẹ. 34 Fi apákan ohun ìní rẹ fún ni, bẹ́ẹ̀ni, àní apákan àwọn ilẹ̀ rẹ, àti gbogbo rẹ̀ bí kò ṣe ìtọ́jú àwọn ẹbí rẹ. 35 San gbèsè tí ìwọ ti jẹ atẹ̀wé. Yọ ara rẹ kúrò nínú ìgbèkùn. 36 Kúrò ní ilé àti ibùgbé rẹ, bíkòṣe nígbàtí ìwọ bá fẹ́ láti rí àwọn ẹbí rẹ. 37 Àti pé sọ̀rọ̀ pẹ̀lú òmìnira sí gbogbo ènìyàn; bẹ́ẹ̀ni, wàásù, gbani níyànjú, kéde òtítọ́, àní pẹ̀lú ariwo, pẹ̀lú ìró ìdùnnú, ní kíkígbe—Hòsánnà, Hòsánnà, ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run! 38 Gbàdúrà nígbà gbogbo, èmi yíò sì tú Ẹ̀mí mi sí orí rẹ, àti pé púpọ̀ ni ìbùkún rẹ yíò jẹ́—bẹ́ẹ̀ni, àní ju bí ìgbà tí ìwọ rí àwọn ohun ìṣúra ti ayé ati àwọn ohun àìtọ́ gbogbo ní ìwọ̀n bí ó ṣe tó. 39 Kíyèsíi, ìwọ ha lè ka èyí láì yọ̀ àti láì gbé ọkàn rẹ sókè fún ìdùnnú? 40 Tàbí ìwọ ha le sáré káàkiri síi gẹ́gẹ́bí afọ́jú adarí? 41 Tàbí ìwọ ha le ní ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́, àti pé kí ìwọ hùwà bí ọlọ́gbọ́n níwájú mi? Bẹ́ẹ̀ni, wá sí ọ̀dọ̀ èmi Olùgbàlà rẹ. Amin. ÌPÍN 20 Ìfihàn lóri àkójọ àti àkóso ìjọ, tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní tàbí nítòsí Fayette, New York. Àwọn abala ìfihàn yìí kan le ti jẹ́ fífúnni láti ìbẹ̀rẹ̀ bíi ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1829. Ìfihàn náà ní pípé, tí a mọ̀ ní àkókò náà bíi Àwọn Nkan ati Àwọn Májẹ̀mú, ni ó ṣeéṣe kí a ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní kété lẹ́hìn ọjọ́ kẹfà Oṣù Kẹrin 1830 (ọjọ tí a ṣe ìgbékalẹ̀ Ìjọ). Wòlíì kọ pé, “A gbà lati ọ̀dọ̀ Rẹ̀ [Jésu Krístì] àwọn àtẹ̀lé wọ̀nyí, nípa ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìfihàn; èyí tí kò fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ nìkan, ṣugbọ́n bákannáà ó tọ́kasí ọjọ́ náà gan an fún wa nígbàtí, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ àti òfin Rẹ̀, a nílati tẹ̀síwájú lati ṣe àkójọ Ìjọ Rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi níhĩn ní orí ilẹ̀ ayé.” 1–16, Ìwé ti Mọ́mọ́nì fi ìdí jíjẹ́ ti ọ̀run iṣẹ́ ọjọ́-ìkẹhìn múlẹ̀; 17–28, Àwọn ẹ̀kọ́ nípa ìṣẹ̀dá, ìṣubú, ètùtù, àti ìrìbọmi ni a fi ìdí wọn múlẹ̀; 29–37, Àwọn òfin tí wọn nṣe àkóso ironúpìwàdà, ìdáláre, ìyàsímímọ́, àti ìrìbọmi ni a fi kalẹ̀; 38–67, Ojúṣe àwọn alàgbà, àlùfáà, olùkọ́, àti àwọn díakonì ni a ṣàlàyé ni ìkékúrú; 68–74, Ojúṣe àwọn omo ìjọ, bíbùkún fún àwọn ọmọdé, àti ọ̀nà ṣíṣe ìrìbọmi ni a fihàn; 75–84, Àwọn àdúrà oúnjẹ alẹ́ Olúwa àti àwọn ìlànà síṣe àkóso jíjẹ́ ọmọ ìjọ ni a fi fúnni. 1 Ìdìde ti Ìjọ Krístì ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn wọ̀nyí, tíí ṣe ẹgbẹ̀rún kan ọgọ́rũn mẹ́jọ ati ọgbọ̀n ọdún lati ìgbà wíwá Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Krístì nínú ẹran ara, òun náà ti a ṣe àkójọ rẹ̀ dáradára àti tí a gbé e kalẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin orílẹ̀ èdè wa, nípa ìfẹ́ inú àti àwọn àṣẹ Ọlọ́run, ní oṣù ìkẹrin, àti ní ọjọ́ ìkẹfà ti oṣù náà èyí tí a npè ní Oṣù Kẹrin— 2 Àwọn òfin èyítí a fi fún Joseph Smith, Kékeré, ẹnití a pè láti ọwọ́ Ọlọ́run, àti tí a yàn gẹ́gẹ́bí àpóstélì ti Jésù Krístì, láti jẹ́ alàgbà àkọ́kọ́ ti ìjọ yìí; 3 Àti sí Oliver Cowdery, ẹnití Ọlọ́run pè bákannáà, àpóstélì kan ti Jésù Krístì, láti jẹ́ alàgbà ìkejì ti ìjọ yìí, tí a sì yàn ní abẹ́ ọwọ́ rẹ̀; 4 Àti èyí gẹ́gẹ́bí oore ọ̀fẹ́ ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Krístì, ẹnití gbogbo ògo jẹ́ tirẹ̀, nísisìyí àti títí lái. Amin. 5 Lẹ́hìn tí a ti fi hàn fún alàgbà àkọ́kọ́ yìí lõtọ́ pe òun ti gba ìmúkúrò àwọn ẹṣẹ̀ rẹ̀, a tún gbé òun dè nínú àwọn ohun asán ayé. 6 Ṣùgbọ́n lẹ́hìn ríronúpìwàdà, àti rírẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, Ọlọ́run ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ sí i láti ọwọ́ ángẹ́lì mímọ́ kan, ẹnití ìwò ojú rẹ̀ dàbíi mọ̀nàmọ́ná, àti ẹnití àwọn aṣọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́ àti funfun ju gbogbo fífunfun míràn lọ; 7 Ó sì fún un ní àwọn òfin èyítí ó mísí i; 8 Àti pé Ó fún un ní agbára láti òkè wá, nípa ọ̀nà èyítí a ti pèsè saájú, láti ṣe ìtumọ̀ Ìwé Ti Mọ́mọ́nì. 9 Èyí tí ó ní àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣubú nínú, àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì sí àwọn Kèfèrí àti sí àwọn Júù bákannáà. 10 Èyítí a fún ni nípa ìmísí, àti tí a fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ sí àwọn míràn nípa ìṣẹ́ ìránṣẹ́ ti àwọn ángẹ́lì, tí a sì kéde rẹ̀ sí ayé nípa wọn— 11 Ní fífihàn sí ayé pé àwọn ìwé mímọ́ jẹ́ òtítọ́, àti pé Ọlọ́run sì nmísí àwọn ènìyàn Ó sì npè wọ́n sí iṣẹ́ mímọ́ rẹ̀ ní àkókò yìí àti ní ìran yìí, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ní àwọn ìran tí ìgbàanì; 12 Nípa bẹ́ẹ̀ Ó nfi hàn pé Òun kannáà ni Ọlọ́run ní àná, ní òní, àti títí láé. Amin. 13 Nítorínáà, níní àwọn ẹlérìí púpọ̀, nípa wọn ni a ó ṣe ìdájọ́ ayé, àní bí wọn ṣe lè jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ tó lẹ́hìnwá tí wọ́n yíò ní ìmọ̀ nípa iṣẹ́ yìí. 14 Àti pé àwọn wọ̃nnì tí wọ́n gbàá nínú ìgbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ òdodo, yíò gba adè kan ti ìyè ayérayé; 15 Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n bá sé ọkàn wọn le nínú àìgbàgbọ́, tí wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yíò yípadà sí ìdálẹbi tiwọn— 16 Nítorí Olúwa Ọlọ́run ti sọ ọ́; àti pé àwa, tí a jẹ́ alàgbà nínú ìjọ, ti gbọ́ a sì ti jẹ́rìí sí àwọn ọ̀rọ̀ ti Ọlọ́lá nlá ológo níbi gíga, sí ẹnití a fi ògo fún láé ati títí láeláe. Amin. 17 Nípa awọn ohun wọ̀nyí ni àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà ní ọ̀run, ẹnití ó jẹ́ àìlópin àti ayérayé, láti àìlópin dé àìlópin Ọlọ́run kan náà tí kò lè yípadà, ẹnití ó ṣe ẹ̀dá ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo èyí tí ó wà nínú wọn; 18 Àti pé ò dá ènìyàn, ọ́kùnrin àti óbìnrin, ní àwòrán ara rẹ̀ àti gẹ́gẹ́bíi ìrí ara rẹ̀, ní ó dá wọn; 19 Àti pé Ó fún wọn ní àwọn òfin pé kí wọ́n ó ní ìfẹ́ kí wọ́n ó sì sìn òun, Ọlọ́run kan ṣoṣo tí ó wà láàyè tí ó sì jẹ́ òtítọ́, àti pé òun nìkan ni ó níláti jẹ́ ẹnití wọ́n ó máa foríbalẹ̀ fún. 20 Ṣùgbọ́n nípa ìwà ìrékọjá sí àwọn òfin mímọ́ wọ̀nyí ènìyàn di ti ara àti ti èṣù, àti pé òun sì di ẹni ìṣubú. 21 Nítorí èyí, Ọlọ́run Alágbára Jùlọ fi Ọmọ Bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, gẹ́gẹ́bí a ṣe kọ́ọ nínú àwọn ìwé mímọ́ wọ̃nnì èyítí a ti fúnni lati ọ̀dọ̀ rẹ̀. 22 Òun sì jìyà àwọn ìdánwò ṣùgbọ́n òun kò fi àkíyèsí rẹ̀ sí wọn. 23 A kàn an mọ́ àgbélèbú, Ó kú, Ó sì tún jínde ní ọjọ́ kẹta; 24 Àti pé Ó gòkè re ọ̀run, láti jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ti Bàbá, láti jọba pẹ̀lú agbára títóbi-jùlọ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú Bàbá; 25 Kí gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi ní orúkọ mímọ́ rẹ̀, àti pé tí wọ́n fi orí tìí nínú ìgbàgbọ́ títí dé òpin, nílati di ẹni ìgbàlà— 26 Kìí ṣe àwọn nìkan tí wọ́n gbàgbọ́ lẹ́hìn tí ó wá ní ààrin gbùngbùn àkókò, nínú ẹran ara, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn wọ̃nnì tí wọ́n gbàgbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, àní gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n wà kí òun tó wá, tí wọ́n gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì mímọ́, tí wọ́n sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti ní ìmísí nípasẹ̀ ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ẹnití ó jẹ́rìí tòótọ́ nípa rẹ̀ nínú ohun gbogbo, nilati ní ìyè ayérayé, 27 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni fún àwọn wọ̃nnì tí wọn yío wá lẹ́hìnáà, tí àwon náà yíò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀bùn àti àwọn ìpè ti Ọlọ́run láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí ó nṣe ìjẹ́rìí nípa Bàbá àti Ọmọ. 28 Tí Bàbá, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ Ọlọ́run kan, àìlópin àti ayérayé, ti kò ní ìparí. Amin. 29 Àti pé àwa mọ̀ pé gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà kí wọ́n ó sì gbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù Krístì, àti kí wọ́n ó bu ọlá fún Bàbá ní orúkọ rẹ̀, àti kí wọn ó fi orí tìí nínú ìgbàgbọ́ ní orúkọ rẹ̀ títí dé òpin, bíbẹ́ẹ̀kọ́ wọn kò ní di ẹni ìgbàlà ní ìjọba Ọlọ́run. 30 Àti pé àwa mọ̀ pé ìdáláre nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Krístì jẹ́ títọ́ àti òtítọ́; 31 Àti pé àwa mọ̀ bákannáà, pé ìyàsímímọ́ nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Krístì jẹ́ títọ́ àti òtitọ́, sí gbogbo àwọn wọ̃nnì tí wọ́n fẹ́ràn tí wọ́n sì ńsìn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo agbára, iyè àti okun wọn. 32 Ṣùgbọ́n ó lè ṣeéṣe kí ènìyàn ṣubú kúrò nínú ore ọ̀fẹ́ kí òun sì yapa kúro lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè; 33 Nítorínáà ẹ jẹ́ kí ìjọ kíyèsára kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí wọ́n má baà bọ́ sínú ìdánwò; 34 Bẹ́ẹ̀ni, àní ẹ sì jẹ́ kí àwọn tí a yà sí mímọ́ náà ó kíyèsára bakannáà. 35 Àti pé àwa mọ̀ pé àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́ àti gẹ́gẹ́bí àwọn ìfihàn Johannù, láì ní àfikún, tàbí àyọkúrò nínú àsọ̀tẹ́lẹ̀ inú ìwé rẹ̀, àwọn ìwé mímọ́, tabí àwọn ìfihàn ti Ọlọ́run tí wọn yíò wá lẹ́hìnnáà nípa ẹ̀bùn àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́, ohùn Ọlọ́run, tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn angẹ́lì. 36 Àti pé Olúwa Ọlọ́run ti sọ ọ́; àti ọlá, agbára àti ògo ni ó yẹ orúkọ mímọ́ rẹ̀, nísisìyí àti títí láe. Amin. 37 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, gẹ́gẹ́bí ọ̀nà àwọn òfin sí ìjọ nípa ìlàna ìrìbọmi—Gbogbo àwọn tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, tí wọn sì níi lọ́kàn láti ṣe ìrìbọmi, tí wọ́n sì jade wá pẹ̀lú írobìnújẹ́ àti ìròra ọkàn, àti tí wọ́n jẹ́rìí níwájú ìjọ pé àwọn ti ronúpìwàdà lõtọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti tí wọ́n ní ìfẹ́ láti gba orúkọ Jésù Krístì sí orí wọn, pẹ̀lú ìpinnu láti sìn ín títí dé òpin, àti tí wọ́n ti fi hàn lõtọ́ nípa iṣẹ́ wọn pé àwọn ti gba lára Ẹ̀mí ti Krístì sí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ni a ó gbà nípa ìrìbọmi sí inú ìjọ rẹ̀. 38 Ojúṣe àwọn alàgbà, àwọn àlùfáà, àwọn olùkọ́, àwọn deakoni, àti àwọn ọmọ ìjọ ti Krístì—àpóstélì jẹ́ alàgbà, àti pé ó jẹ́ ìpè rẹ̀ lati ṣe ìrìbọmi; 39 Àti láti yan àwọn alàgbà míràn, àwọn àlùfáà, àwọn olùkọ́, àti àwọn díákónì. 40 Àti láti ṣe àkóso àkàrà àti wáìnì—àwọn àpẹrẹ ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ ti Krístì— 41 Àti láti fì ẹsẹ̀ àwọn wọ̃nnì múlẹ̀ tí a rìbọmi sínú ìjọ, nípa gbígbé ọwọ́ lé wọn lórí fún ìrìbọmi ti iná àti ti Ẹ̀mí Mímọ́, ní ìbámu sí àwọn ìwé mímọ́; 42 Àti láti kọ́ni, sọ àsọyé, gbàni nímọ̀ràn, rìbọmi, ati dáàbò bo ìjọ; 43 Àti láti fi ìdí ìjọ múlẹ̀ nípa gbígbé ọwọ́ léni lórí, àti fífúnni ní Ẹ̀mí Mímọ́; 44 Àti láti darí gbogbo àwọn ìpàdé. 45 Àwọn alàgbà ni wọ́n nílati darí àwọn ìpàdé bí Ẹ̀mí Mímọ́ bá ṣe darí wọn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti àwọn ìfihàn ti Ọlọ́run. 46 Ojúṣe àlùfáà ni láti wàásù, kọ́ni, sọ àsọyé, gbani níyànjú, àti ṣe ìrìbọmi, àti ṣe àkóso ouńjẹ àlẹ́ Olúwa, 47 Àti láti ṣe àbẹ̀wò sí ilé ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ ìjọ, kí ó sì gbà wọ́n níyànjú láti máa gbàdúrà lóhùn òkè àti ní ìkọ̀kọ̀, àti láti máa ṣe gbogbo àwọn ojúṣe ẹbí. 48 Àti pé bákannáà òun lè yan àwọn àlùfáà míràn, àwọn olùkọ́ni, àti àwọn díákónì. 49 Àti pé òun ni yíò darí àwọn ìpàdé nígbàtí alàgbà kankan kò bá sí níbẹ̀. 50 Ṣùgbọ́n nígbàtí alàgbà kan bá wá níbẹ̀, òun ó kàn wàásù, kọ́ni, sọ àsọyé, gbani níyànjú, àti ṣe ìrìbọmi. 51 Àti láti ṣe àbẹ̀wò sí ilé ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ ìjọ, ní gbígbà wọ́n níyànjú láti máa gbàdúrà lóhùn òkè àti ní ìkọ̀kọ̀, àti láti ṣe gbogbo àwọn ojúṣe ẹbí. 52 Nínú gbogbo ojúṣe wọ̀nyí, àlùfáà níláti ṣe àtìlẹ́hín fún alàgbà bí ó bá yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. 53 Ojúṣe olùkọ́ni ni láti ṣe àbójútó ìjọ nígbà gbogbo, láti wà pẹ̀lú wọn àti láti máa mú wọn lọ́kàn le; 54 Àti lati ríi pé kò sí àìṣedẽdé nínú ìjọ, tàbí ìṣòro pẹ̀lú ẹnìkan sí ẹlòmíràn, tàbí irọ́ pípá, tàbí sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀ni lẹ́hìn, tàbí sísọ̀rọ̀ búburú; 55 Ati lati ríi pé ìjọ nní ìpàde papọ̀ nígbàkúùgbà, àti bákannáà lati ríi pé gbogbo ọmọ ìjọ nṣe ojúṣe wọn. 56 Àti pé òun ni yíò darí àwọn ìpàdé bí alàgbà tàbí àlùfáà kankan kò bá sí níbẹ̀— 57 Ati pé àwọn diakónì yíò máa ràn án lọ́wọ́ nígbà gbogbo, nínú gbogbo iṣẹ rẹ̀ nínú ìjọ bí ó bá yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. 58 Ṣùgbọ́n kò sí olùkọ́ni tàbí diakonì tí ó ní àṣẹ láti ṣe ìrìbọmi, ṣe àkóso ouńjẹ alẹ́ Olúwa, tàbí gbé ọwọ́ lé ni lórí; 59 Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn wà, lati ṣe ìkìlọ̀, sọ àsọyé, gbani níyànjú, àti kọ́ni, àti lati pè gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ Krístì. 60 Olukúlùkù alàgbà, àlùfáà, olùkọ́ni, tàbí díakonì ni a ó yàn ní ìbámu pẹ̀lú awọn ẹ̀bùn àti awọn ìpè Ọlọ́run sí i; àti pé a ó yàn an pẹ̀lú agbára Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí ó wà nínú ẹnití ó yàn án. 61 Onírúurú àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ ti ìjọ Krístì yìí yíò máa ní ìpádé nínú àpéjọpọ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan láàrin oṣù mẹ́ta, tàbí láti àkókò dé àkókò bí àpéjọpọ̀ náà bá ṣe darí tàbí fi ọwọ́ sí; 62 Àti pé àwọn àpéjọpọ̀ tí a sọ yìí ni yíò máa ṣe èyíkéyìí iṣẹ́ ìjọ tí ó bá yẹ ní ṣíṣe ní ìgbà náà. 63 Àwọn alàgbà nílati gba àwọn ìwé àṣẹ wọn ní ọwọ́ àwọn alàgbà míràn, nípa ìbò àwọn ọmọ ìjọ èyí tí wọ́n wà, tàbí nínú àwọn àpéjọpọ̀. 64 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àlùfáà, olùkọ́ni, tàbí díakonì, ẹnití a yàn láti ọwọ́ àlùfáà, lè gba ìwé ẹ̀rí lọ́wọ́ rẹ̀ ní àkókò náà, ìwé ẹ̀rí èyítí ó jẹ́ pé, bí a bá fún alàgbà kan, yíò kà òun yẹ fún ìwé àṣẹ, tí yíò fi àṣẹ fún un láti ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó rọ̀ mọ́ ìpè rẹ̀, tàbí òun lè gbà á nínú ìpádé àpéjọpọ̀ kan. 65 A kò gbọdọ̀ yan ẹnikẹ́ni sí ipò kankan nínú ìjọ yìí, níbití àkójọ ẹ̀ka dáradára ti ìkannáà wà, láì sí ìbò ìjọ náà; 66 Ṣùgbọ́n àwọn alàgbà tí wọ́n nṣe olórí, àwọn bíṣọpù tí wọn nrin ìrìnàjò, àwọn ọmọ àjọ ìgbìmọ̀ gíga, àwọn àlùfáà gíga, àti àwọn alàgbà, lè ní ànfàní yíyanni, ní ibití kò bá sí ẹ̀ka ìjọ tí a lè ti pe ìbò. 67 Ààrẹ kọ̀ọ̀kan nínú oyè àlùfáà gìga (tàbí alàgbà tí ó nṣe olórí), bíṣọ́ọ̀pù, ọmọ àjọ ìgbìmọ̀ gíga, àti àlùfáà gíga, ni a ó yàn lábẹ́ ìdarí àjọ ìgbìmọ̀ gíga tàbí nínú ìpàdé àpéjọpọ̀ gbogbogbòò. 68 Ojúṣe àwọn ọmọ ìjọ lẹ́hìn tí a ti gbà wọ́n wọlé nípa ìrìbọmi—Àwọn alàgbà tàbí àwọn àlùfáà nílati ní ànító àkókò lati sọ àsọyé ohun gbogbo nípa ìjọ ti Krístì bí ó ṣe yé wọn tó, saájú kí wọ́n ó tó jẹ oúnjẹ alẹ́ Olúwa, àti kí a tó fi ìdí wọn múlẹ̀ nípa gbígbé ọwọ́ léni lórí láti ọwọ́ àwọn alàgbà, kí á lè ṣe ohun gbogbo pẹ̀lú ètò. 69 Àti pé àwọn ọmọ ìjọ yíò fihàn ní iwájú ìjọ, àti bákannáà níwájú àwọn alàgbà, nípa ìrìn bí Ọlọ́run àti ìsọ̀rọ̀, pé wọ́n yẹ fún un, pé kí àwọn iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ lè wà ní ìbámu sí àwọn ìwé mímọ́—rírìn ní mímọ́ níwájú Olúwa. 70 Olúkúlùkù ọmọ ìjọ ti Krístì tí ó bá ní ọmọ wẹ́wẹ́ ni ó níláti mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà níwáju ìjọ, àwọn tí wọn yíò gbé ọwọ́ lé wọn lórí ní orúkọ Jésù Krístì, tí wọn yíò sì súre fún wọn ní orúkọ rẹ̀. 71 A kò lè gba ẹnikẹ́ni sínú ìjọ ti Krístì bíkòṣepé òun ti dàgbà dé awọn ọdún ṣíṣe ìṣirò níwáju Ọlọ́run, àti tí ó ti lè ṣe ìrònúpìwàdà. 72 Ìrìbọmi ni a nílati ṣe àkóso rẹ̀ ní ọ̀nà tí a là sílẹ̀ yìí fún gbogbo àwọn wọ̃nnì tí wọ́n ronúpìwàdà— 73 Ẹni náà tí Ọlọ́run pè tí ó sì ní àṣẹ láti ọdọ̀ Jésù Krístì láti rìbọmi, yíò sọkalẹ̀ lọ sínú omi pẹ̀lú ẹni náà tí ó ti fa ara rẹ̀ kalẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin fún ìrìbọmi, òun yíò sì sọ pé, ní pípe ẹni náà lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin ní orúkọ rẹ̀: Nítorí tí a ti fi àṣẹ fúnmi lati ọ̀dọ̀ Jésù Krístì, mo rì ọ́ bọmi ní orúkọ ti Bàbá, àti ní ti Ọmọ, àti ní ti Ẹ̀mí Mímọ́. Àmín. 74 Nígbànáà ni òun yíò ri ẹni náà lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin bọ inú omi, yíò sì tún mú un jade wá láti inú omi náà. 75 O ṣe ànfààní pé kí ìjọ máa pàdé papọ̀ lóòrèkóòrè láti ṣe àbápín ti àkàrà àti wáìnì ní ìrántì Olúwa Jésù; 76 Àti pé alàgbà tàbí àlùfáà yíò ṣe ìpínfúnni rẹ̀; ní ọ̀nà yìí ni òun yíò sì ṣe ìpínfúnni rẹ̀—òun yíò kúnlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọ yíò sì ké pe Bàbá nínú àdúrà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wipe: 77 Áà Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, àwa béèrè lọ́dọ̀ rẹ ní orúkọ Ọmọ rẹ, Jésù Krístì, láti súre àti lati yà àkàrà yìí sí mímọ́ sí ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹnití ó ní ìpín nínú rẹ̀, kí wọ́n lè jẹ ní ìrántí ti ara Ọmọ rẹ, àti kí wọ́n jẹ́rìí sí ọ, Áà Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, pé wọ́n fẹ́ láti gba orúkọ Ọmọ rẹ sí órí wọn, àti láti rántí rẹ̀ nígbàgbogbo àti láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ èyítí ó ti fi fún wọn; pé kí wọn lè ní Ẹ̀mí rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wọn nígbàgbogbo. Àmín. 78 Ọ̀nà tí a fi nṣe ìpínfúnni wáìnì—òun yíò mú ago náà pẹ̀lú, yíò sì wipe: 79 Áà Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, àwa béèrè lọ́dọ̀ rẹ ní orúkọ Ọmọ rẹ, Jésù Krístì, láti súre àti lati ya wáìnì yìí sí mímọ́ sí ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹnití ó mu nínú rẹ̀, pé kí wọ́n lè ṣeé ní ìrántí ti ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ, èyítí a ta sílẹ̀ fún wọn; pé kí wọ́n lè jẹrìí sí ọ, Áà Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, pé wọ́n nrántí rẹ̀ nígbàgbogbo, pé kí wọn lè ní Ẹ̀mí rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wọn. Àmín. 80 Èyíkéyìí ọmọ ìjọ ti Krístì tí ó bá nṣe ìrékọjá, tàbí tí a bá mú nínú ìṣubú kan, ni a ó ṣe sí gẹ́gẹ́bí àwọn ìwé mímọ́ ṣe darí. 81 Yíò jẹ́ ojúṣe onírúurú awọn ìjọ, tí àpapọ̀ wọ́n jẹ́ ìjọ ti Krístì, láti rán ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn olùkọ́ wọn láti wà ní ibi onírúurú àwọn àpéjọpọ̀ síṣe lati ọwọ́ àwọn alàgbà ìjọ, 82 Pẹ̀lú títò lẹ́sẹẹsẹ àwọn orúkọ ti onírúurú àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n ti ṣe ara wọn ní ọ̀kan pẹ̀lú ìjọ lẹ́hìn àpéjọpọ̀ tí ó kẹ́hìn; tàbí fífi ránṣẹ́ láti ọwọ́ àwọn àlùfáà kan; kí títò lẹ́sẹẹsẹ dáradára kan ti gbogbo awọn orúkọ inú ìjọ pátápátá baà le wà ní pípamọ́ ńinú ìwé kan lati ọwọ́ ọ̀kan nínú àwọn alàgbà, ẹnikẹ́ni tí àwọn alàgbà yókù lè yàn láti àkókò dé àkókò; 83 Àti bákannáà, bí a bá ti lé ẹnikẹ́ni kúrò nínú ìjọ, kí á lè pa orúkọ wọn rẹ́ nínú ìwé àkọsílẹ̀ awọn orúkọ gbogbogbòò ti ìjọ. 84 Gbogbo ọmọ ìjọ tí wọ́n bá ńkúrò nínú ìjọ ní ibití wọ́n ngbé, tí wọ́n bá nlọ sí ìjọ tí a kò ti mọ̀ wọ́n, wọ́n lè gba ìwé ṣíṣe ẹ̀rí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ìjọ dáradára ati tí ó nṣe déédé, ìwé ẹ̀rí èyítí ó lè ní ìfọwọ́sí èyíkéyìí alàgbà tàbí àlùfáà kan bí ọmọ ìjọ tí ó fẹ́ gba ìwé ẹ̀rí náà jẹ́ ẹni mímọ̀ fún alàgbà tàbí àlùfáà náà, tàbí kí àwọn olùkọ́ni tàbí àwọn díakonì ìjọ fi ọwọ́ sí i. ÌPÍN 21 Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith ní Fayette, New York, 6 Oṣù Kẹrin 1830. Ìfihàn yìí ni a fi fúnni ní àkókò tí à nṣe àkójọ ìjọ, ní ọjọ́ tí a dárúkọ yìí, nínú ilé Peter Whitmer Àgbà. Àwọn ọkùnrin mẹ́fà, tí a ti ṣe ìrìbọmi fún tẹ́lẹ̀, ni wọ́n kópa. Pẹ̀lú ìfohùnṣọ̀kan ìbò, àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi èrò ọkàn àti ìpinnu wọn hàn láti ṣe àkójọ, ní ìbámu sí àṣẹ Ọlọ́run (wo ìpín 20). Wọ́n tún di ìbò bákannáà láti gba wọlé ati lati ṣe àtìlẹhìn Joseph Smith Kekeré àti Oliver Cowder gẹ́gẹ́bí àwon olórí òṣìṣẹ́ ti ìjọ. Pẹ̀lú gbígbé ọwọ́ léni lórí, nígbànáà Joseph yan Oliver bíi alàgbà ìjọ, Oliver náà sì yan Joseph ní ọ̀nà kannáà. Lẹ́hìn ṣíṣe ìpínfúnni oúnjẹ alẹ́ Olúwa, Joseph àti Oliver gbé ọwọ́ lé àwọn olùkópa lórí ní ẹnìkọ̀ọ̀kan fún ìfifúnni Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún fifi ìdí ẹnìkọ̀ọ̀kan múlẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọmọ ìjọ. 1–3, A pe Joseph Smith lati jẹ́ aríran, olùtúmọ̀, wòlíì, àpóstélì, àti alàgbà; 4–8, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yíò ṣe ìtọ́ni sí ipa ọ̀nà Síónì; 9–12, Àwọn ènìyàn mímọ́ yíò gba àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́ bí òun ṣe ńsọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmísí Olùtùnú. 1 Kíyèsíi, àkọsílẹ̀ kan ni a ó pamọ́ ní ààrin yín; àti nínú rẹ̀ a ó pè ọ́ ní aríran, olùtúmọ̀, wòlíì, àpóstélì ti Jésù Krístì, alàgbà ti ìjọ nipa ìfẹ́ inú ti Ọlọ́run Bàbá, àti oore ọ̀fẹ́ Olúwa rẹ Jésù Krístì, 2 Nítorí tí ó ní ìmísí ti Ẹ̀mí Mímọ́ láti fi ìpìlẹ̀ náà lélẹ̀, àti lati kọ́ọ sókè sí ìgbàgbọ́ mímọ́ jùlọ. 3 Ìjọ èyítí a ṣe àkójọ rẹ̀ àti tí a gbé kalẹ̀ nínú ọdún Olúwa rẹ ọgọ́rũn méjìdínlógún ati ọgbọ̀n, ní oṣù kẹrin, àti ní ọjọ́ kẹfà ti oṣù èyítí à npè ní Oṣù Kẹrin. 4 Nítorí-èyí, tí ó túmọ̀ sí ìjọ, ẹ níláti ṣe àkíyèsíi gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ àti àwọn àṣẹ èyítí òun yíò fi fún yín bí òun náà ṣe gbà wọ́n, rírìn ní gbogbo ìwà mímọ́ níwájú mi; 5 Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ẹ̀yin yíó gbà, bí ẹnipé láti ẹnu tèmi, pẹ̀lú gbogbo sùúrù àti ìgbàgbọ́. 6 Nítorí nípa síṣe àwọn ohun wọ̀nyí àwọn ẹnu ọ̀na ọ̀run àpáàdì kì yíò lè borí yín; bẹ́ẹ̀ni, àti pé Olúwa Ọlọ́run yíò tú gbogbo agbára òkùnkùn ká ní iwájú yín, àti yíò mú kí ọ̀run ó mì tìtì fún ire yín, àti nítorí ogo orúkọ rẹ̀. 7 Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Òun ni èmi ti mísí láti mú kí ipa ọ̀nà Síónì kí ó tẹ̀ síwájú nínú agbára nlá fún ire, àti aápọn rẹ̀ ni èmi mọ̀, èmi sì ti gbọ́ àwọn àdúrà rẹ̀. 8 Bẹ́ẹ̀ni, ẹkún rẹ̀ fún Síónì ni èmi ti rí, èmi yíò sì mú kí òun máṣe ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀ mọ́; nítorí ìgbà inú dídùn rẹ̀ ti dé sí ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, àti àwọn ìfarahàn àwọn ìbùkún mi lórí àwọn iṣẹ́ rẹ̀. 9 Nítorí, kíyèsíi, èmi yíò bùkún fún àwọn wọ̃nnì tí wọ́n ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajarà mi pẹ̀lú ìbùkún nlá, wọn yíò sì gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, èyítí a fi fún òun nípasẹ̀ èmi lati ọwọ́ Olùtùnú, èyítí ó sọ ọ di mímọ̀ pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n kan Jésù mọ́ àgbélèbú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ arayé, bẹ́ẹ̀ni, fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ sí ìròbìnújẹ́ ọkàn. 10 Nísisìyí, ó jẹ́ dandan fún mi pé kí á yàn án láti ọwọ́ rẹ, Oliver Cowdery àpóstélì mi; 11 Èyí jẹ́ ìlànà kan fún ọ, pé ìwọ jẹ́ alàgbà ní abẹ́ ìgbọ́wọ́lé lórí rẹ̀, òun sì jẹ́ àkọ́kọ́ sí ìwọ, pé kí ìwọ baà lè jẹ́ alàgbà sí ìjọ ti Krístì, tí ó ńjẹ́ orúkọ mi— 12 Àti oníwàásù àkọ́kọ́ ti ìjọ yìí fún ìjọ, àti níwájú ayé, bẹ́ẹ̀ni, ní iwájú àwọn Kèfèrí; bẹ́ẹ̀ni, àti bayìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, wòó, wòó! sí àwọn Júù bákannáà. Àmín 1 Nífáì bẹ̀rẹ̀ ìwé ìrántí àwọn ènìyàn rẹ̀—Léhì ríran rí ọwọ̀n iná kan ó sì kà láti inú ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ kan—Ó yin Ọlọ́run, ó sọ nípa bíbọ̀ Messia nã, ó sì sọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù—A ṣe inúnibíni sí i nípasẹ̀ àwọn Jũ. Ní ìwọ̀n ọdún 600 kí á tó bí Olúwa wa. ÈMI, Nífáì, nítorí tí a bí mi nípa àwọn òbí dídára, nítorínã a kọ́ mi nínú gbogbo òye bàbá mi; àti nítorí pé mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú ní ìgbà àwọn ọjọ́ mi, bíótilẹ̀ríbẹ̃, nítorí tí mo ti rí ojúrere Olúwa lọ́pọ̀ ní gbogbo àwọn ọjọ́ mi; bẹ̃ni, nítorí pé mo ti ní ìmọ̀ nla nípa ọ́re àti àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, nítorínã mo ṣe ìwé ìrántí àwọn ìṣe mi ní àwọn ọjọ́ mi. Bẹ̃ni, mo ṣe ìwé ìrántí ní èdè bàbá mi, èyí tí ó ní òye àwọn Jũ àti èdè àwọn ará Égíptì. Mo sì mọ̀ wí pé ìwé ìrántí èyí tí mo ṣe jẹ́ òtítọ́; mo sì ṣe é pẹ̀lú ọwọ́ ara mi; mo sì ṣe é gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ mi. Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kíní ti ìjọba Sẹdẹkíàh, ọba Júdà, (bàbá mi, Léhì, tí ó ti gbé ní Jerúsálẹ́mù ní gbogbo àwọn ọjọ́ rẹ̀); àti ní ọdún kan nã yĩ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlĩ wá, wọ́n n sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn wí pé wọn gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà, bíbẹ̃kọ́ ìlú nlá nì Jerúsálẹ́mù yíò di píparun. Nítorí-èyi ó sì ṣe pé bàbá mi, Léhì, bí ó ṣe jáde lọ ó gbàdúrà sí Olúwa, bẹ̃ni, àní pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, fún ànfàní àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó sì ṣe bí ó ṣe n gbàdúrà sí Olúwa, ọwọ̀n iná kan wá ó sì wà lórí àpáta níwájú rẹ̀; ó sì rí, ó sì gbọ́ púpọ̀; nítorí àwọn ohun tí ó rí àti tí ó gbọ́ ó gbọ̀n ó sì wárìrì lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó sì ṣe pé ó padà sí ilé tirẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù; ó sì ju ara rẹ̀ sí orí ibùsùn rẹ̀, nítorí tí a borĩ rẹ̀ pẹ̀lú Ẹ̀mí àti àwọn ohun èyí tí ó ti rí. Nítorí tí a borí rẹ̀ báyĩ pẹ̀lú Ẹ̀mí, a mú un lọ nínú ìran, àní tí ó fi rí àwọn ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, ó sì wòye pé òun rí Ọlọ́run tí ó jóko lórí ìtẹ́-ọba rẹ̀, tí àjọ àìníye àwọn angẹ́lì si yĩ ka ní ìwà kíkọrin àti yíyin Ọlọ́run wọn. Ó sì ṣe pé ó rí Ẹnìkan tí ó n sọ̀kalẹ̀ láti ãrín ọ̀run, ó sì ri pé ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ pọ̀ ju ti ọ́rùn ní agbedeméjì ọjọ́. Ó sì tún rí àwọn méjìlá kan tí wọ́n n tẹ̀lé e, tí dídán wọn sì tayọ ti ìràwọ̀ ní òfúrufú. Wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ wọ́n sì lọ kãkiri ní ojú-ilẹ̀ àgbáyé; ẹni ìṣãjú sì wá ó sì dúró níwájú bàbá mi, ó sì fún un ní ìwé kan, ó sì fi àṣẹ fún un pé kí ó kà á. Ó sì ṣe pé bí ó ṣe n kà á, ó kún fún Ẹ̀mí Olúwa. Ó sì kà á, wí pé: Ègbé, ègbé ni fún Jerúsálẹ́mù, nítorí mo ti rí àwọn ohun ìríra rẹ! Bẹ̃ni, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan sì ni bàbá mi kà nípa Jerúsálẹ́mù—pé a ó pãrun, àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; ọ̀pọ̀ ni yíò ṣègbé nípasẹ̀ idà, ọ̀pọ̀ sì ni a ó kó ní ìgbèkùn lọ sí Bábílọ́nì. Ó sì ṣe nígbà tí bàbá mi ti kà á tí ó sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nlá àti àwọn ohun ìyanu, ó kígbe àwọn ohun púpọ̀ sókè sí Olúwa; bíí: Títóbi àti ìyanu ni iṣẹ́ rẹ, A! Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè! Ìtẹ́-ọba rẹ ga ní òkè-ọ̀run, bẹ̃ni agbára rẹ, àti ọ́re, àti ãnú nbẹ lórí gbogbo olùgbé ayé; àti, nítorí tí ìwọ jẹ́ aláanú, ìwọ kì yíò yọ̣́da àwọn tí ó bá wá sọ́dọ̀ rẹ pé kí wọ́n ó ṣègbé! Bí irú eleyĩ sì ni èdè bàbá mi ní yínyin Ọlọ́run rẹ̀; nítorí ọkàn rẹ̀ yọ̀, gbogbo ọkàn rẹ̀ sì kún, nítorí àwọn ohun èyí tí ó ti rí, bẹ̃ni, èyí tí Ọlọ́run ti fihàn án. Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kò sì ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwé ìtàn àwọn ohun èyí tí bàbá mi ti kọ, nítorí tí ó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun èyí tí ó rí nínú àwọn ìran àti àlá; ó sì ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun pẹ̀lú, èyí tí ó sọtẹ́lẹ̀ tí ó sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀, nípa èyí tí èmi kò ní ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwé ìtàn. Ṣùgbọ́n èmi yíò ṣe ìwé ìtàn àwọn ìṣe mi ní àwọn ọjọ̣́ mi. Kíyèsĩ, mo ṣe ìkékúrú ìwé ìrántí bàbá mi, sórí awọn àwo èyí tí mo ti ṣe pẹ̀lú ọwọ́ ara mi; nítorí-èyi, lẹ́hìn tí mo bá ti ké ìwé ìrántí bàbá mi kúrú nígbà nã ni èmi yíò ṣe ìwé ìtàn ti ìgbésí ayé tèmi. Nítorínã, mo fẹ́ kí ẹ̀yin mọ̀, pé lẹ́hìn tí Olúwa ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìyanu han sí bàbá mi, Léhì, bẹ̃ni, nípa ìparun Jerúsálẹ́mù, kíyèsĩ ó jáde lọ sí ãrín àwọn ènìyàn nì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọtẹ́lẹ̀ ó sì n kéde sí wọn nípa àwọn ohun èyí tí ó ti rí àti tí ó ti gbọ́. Ó sì ṣe tí àwọn Jũ fi ṣe ẹlẹ́yà nítorí àwọn ohun èyí tí ó jẹ́rĩ sí nípa wọn; nítorí tí ó jẹ́rĩ nítọ́tọ́ sí ìwà búburú wọn àti àwọn ohun ìríra wọn; ó sì jẹ́rĩ pé àwọn ohun èyí tí òun rí tí òun sì gbọ́, àti pẹ̀lú àwọn ohun èyí tí òun kà nínú ìwé nã, fi hàn kedere bíbọ̀ Messia kan, àti pẹ̀lú ìràpadà ayé. Nígbà tí àwọn Jũ sì gbọ́ àwọn nkan wọ̀nyí wọ́n bínú sí i; bẹ̃ni, àní, bĩ sí àwọn wòlĩ ìgbà àtijọ́, tí wọ́n ti sọ sóde, tí wọ́n sì sọ ní òkúta, tí wọ́n sì pa; wọ́n sì tún wá ẹ̀mi rẹ̀, kí wọ́n lè mú un kúrò. Ṣùgbọ́n kíyèsí i, èmi, Nífáì, yíò fihàn sí yín pé ãnú Olúwa tíó ní ìtùnú nbẹ lórí gbogbo àwọn ẹni tí ó ti yàn, nítorí ti ìgbàgbọ́ wọn, láti ṣe wọ́n ní alágbára àní sí agbára ìdásílẹ̀. 2 Léhì mú ìdílé rẹ̀ lọ sínú ijù lẹ́bã Òkun Pupa—Wọ́n fi ohun ìní wọn sílẹ̀—Léhì rúbọ sí Olúwa ó sì kọ́ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti pa àwọn òfin mọ́—Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì kùn sí bàbá wọn—Nífáì ṣe ígbọràn ó sì gbàdúrà ní ìgbàgbọ́; Olúwa bã sọ̀rọ̀, a sì yàn án láti jọba lórí àwọn arákùnrin rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 600 kí á tó bí Olúwa wa. Nítorí kíyèsĩ i, ó sì ṣe tí Olúwa bá bàbá mi sọ̀rọ̀, bẹ̃ni, àní nínú àlá, ó sì sọ fún un: Alábùkún fún ni ìwọ Léhì, nítorí àwọn ohun èyí tí ìwọ ti ṣe; àti nítorí ìwọ ti jẹ́ olóotọ́ tí ìwọ sì ti kéde sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, àwọn ohun èyí tí mo pàṣẹ fún ọ, kíyèsĩ i, wọ́n n wá láti mú ẹ̀mí rẹ kúrò. Ó sì ṣe tí Olúwa pàṣẹ fún bàbá mi, àní nínú àlá, pé kí ó mú ìdílé rẹ̀ kí ó sì lọ kúrò sínú ijù. Ó sì ṣe tí ó ṣe ígbọràn sí ọ̀rọ̀ Olúwa, nítorí-èyi, ó ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún un. Ó sì ṣe tí ó lọ kúrò sínú ijù. Ó sì fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, àti ilẹ̀ ìní rẹ̀, àti wúrà rẹ̀, àti fàdákà rẹ̀, àti àwọn ohun oníyebíye rẹ̀, kò sì mú ohunkóhun pẹ̀lú rẹ̀, àfi ìdílé rẹ̀, àti àwọn èsè, àti àwọn àgọ́, ó sì lọ kúrò sínú ijù. Ó sì wá sísàlẹ̀ ní ẹ̀bá itòsí èbúté Òkun Pupa; ó sì rin ìrìn-àjo nínú ijù ní ẹ̀bá èyí tí ó wà nítòsí Òkun Pupa; ó sì rin ìrìn-àjò nínú ijù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, èyí tí i ṣe ìyá mi, Sáráíà, àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, tí wọ́n jẹ́ Lámánì, Lẹ́múẹ́lì, àti Sãmú. Ó sì ṣe pé nígbà tí ó ti rin ìrìn-àjò ọjọ́ mẹ́ta nínú ijù, ó tẹ àgọ́ rẹ̀ sí àfonífojì lẹ́bã ẹ̀gbẹ́ odò omi kan. Ó sì ṣe tí ó kọ́ pẹpẹ òkúta kan, ó sì ṣe ọrẹ kan sí Olúwa, ó sì fi ọpẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run wa. Ó sì ṣe tí ó pe orúkọ odò nã ní, Lámánì, ó sì n ṣàn sínú Òkun Pupa; àfonífojì nã sì wà ní ẹ̀bá itòsí ẹnu rẹ̀. Àti nígbàtí bàbá mi sì rí i wí pé omi odò nã nṣàn sínú ìsun Òkun Pupa, ó wí fún Lámánì, wí pé: À! ìwọ ìbá lè dàbí odò yĩ, tí ó nṣan títí sínú orísun gbogbo ìwà òdodo! Ó sì tún wí fún Lẹ́múẹ́lì: À! ìwọ ìbá lè dàbí àfonífojì yĩ, tí ó wà gbọn-in tí ó sì dúróṣinṣin, tí kò sì lè mì ní pípa àwọn òfin Olúwa mọ́! Nísisìyí èyí ni ó wí nítorí ti ọrùn líle Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì; nítorí kíyèsĩ i wọ́n n kùn sínú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun sí bàbá wọn, nítorí tí ó jẹ́ aríran ọkùnrin, ó sì ti tọ́ wọn jáde ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, láti kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn, àti wúrà wọn, àti fàdákà wọn, àti àwọn nkan oníyebíye wọn, láti ṣègbé nínú ijù. Èyí sì ni wọ́n sọ wí pé ó ti ṣe nítorí ti ìrò aláìgbọ́n ọkàn rẹ̀. Báyĩ s ì ni Lámánì à t i Lẹ́múẹ́lì, tí wọ́n jẹ́ agba, kùn sì bàbá wọn. Wọ́n sì kùn nítorí tí wọn kò mọ́ ìbálò Ọlọ́run nì, ẹni tí ó dá wọn. Bẹ̃ni wọn kò gbàgbọ́ wí pé Jerúsálẹ́mù, ìlú nla nì, lè parun gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ. Wọ́nsì dàbí àwọn Jũ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n n wá láti mú ẹ̀mí bàbá mi kúrò. Ó sì ṣe tí bàbá mi bá wọn sọ̀rọ̀ ní àfonífojì Lẹ́múẹ́lì, pẹ̀lú agbára, nítorí tí ó kún fún Ẹ̀mí, títí di ìgbà tí ara wọ́n fi gbọ̀n níwájú rẹ̀. Ó sì dãmú wọn, tí wọn kò fi lè sọ̀rọ̀ lòdì sí i; nítorí-èyi, wọ́n ṣe bí ó ṣe pàṣẹ fún wọn. Bàbá mi sì gbé nínú àgọ́ kan. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, nítorí tí mo jẹ ọmọdé lọ́pọ̀lọpọ̀, bíótilẹ̀ríbẹ̃ tí mo tóbi ní ìnà sókè ènìyàn, àti pẹ̀lú nítorí tí mo ní ìfẹ́ nlá láti mọ̀ nípa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, nítorí-èyi, mo kígbe pe Olúwa; sì kíyèsĩ i ó sì bẹ̀ mí wò, ó sì mú ọkàn mi rọ̀ tí mo fi gba gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ nã gbọ́, èyí tí bàbá mi ti sọ; nítorí-èyi, èmi kò ṣọ̀tẹ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin mi. Mo sì bá Sãmú sọ̀rọ̀, mo jẹ́ kí ó mọ̀ nípa àwọn ohun tí Olúwa ti fihàn sí mi nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́. Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ i, Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì kò fẹ́ fetísílẹ̀ sí awọn ọ̀rọ̀ mi; nítorí tí inú mi sì bàjẹ́ nítorí líle ọkàn wọn mo kígbe pe Olúwa fún wọn. Ó sì ṣe tí Olúwa wí fún mi, wí pé: Alábùkún-fún ni ìwọ, Nífáì, nítorí ìgbàgbọ́ rẹ, nítorí ìwọ ti wá mi lẹ́sọ̀lẹsọ̀, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn. Níwọ̀n bí ìwọ bá sì n pa àwọn òfin mi mọ́, ìwọ yíò ṣe rere, a ó sì ṣe amọ̀nà rẹ lọ sí ilẹ̀ ìlérí kan; bẹ̃ni, àní ilẹ̀ èyí tí mo ti pèsè fún ọ; bẹ̃ni, ilẹ̀ èyí tí ó jẹ́ àṣàyàn ju gbogbo àwọn ilẹ̀ míràn. Níwọ̀n bí àwọn arákùnrin rẹ bá sì n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ, a ó gé wọn kúrò níwájú Olúwa. Níwọ̀n bí ìwọ bá sì n pa àwọn òfin mi mọ́, a ó fi ọ́ ṣe alákòso àti olùkọ́ lórí àwọn arákùnrin rẹ. Nítorí kíyèsĩ i, ní ọjọ́ nã tí wọ́n bá ṣọ̀tẹ̀ sí mi, èmi yíò fi wọ́n bú àní pẹ̀lú ìfibú kíkan, nwọn kì yíò sì ní agbára lórí irú-ọmọ rẹ àfi tí wọ́n ó bá ṣọ̀tẹ̀ sí èmi nã pẹ̀lú. Bí ó bá sì ṣe pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, wọn yíò j ẹ́ pàṣán fún irú-ọmọ rẹ, láti rú wọn sókè ní àwọn ọ̀nà ìrantí. 3 Àwọn ọmọkùnrin Léhì padà sí Jerúsálẹ́mù láti gba àwọn àwo idẹ—Lábánì kọ̀ láti fi àwọn àwo nã sílẹ̀—Nífáì gba àwọn arákùnrin rẹ̀ níyànjú ó sì mú wọn lọ́kàn le—Lábánì j í ohun ìní wọn ó sì gbìdánwò láti pa wọ́n—Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì lu Nífáì àti Sãmú, angẹ́lì kan sì bá wọn wí. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, padà láti sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú Olúwa, sí àgọ́ bàbá mi. Ó sì ṣe tí ó wí fún mi, wí pé: Kíyèsĩ i mo ti lá àlá kan, nínú èyí tí Olúwa ti pàṣẹ fún mi pé ìwọ àti àwọn arákùnrin rẹ yíò padà sí Jerúsálẹ́mù. Nítorí kíyèsĩ i, Lábánì ní ìwé ìrántí àwọn Jũ àti pẹ̀lú ìtàn ìdílé àwọn baba-nlá mi, a sì fín wọn sórí àwọn àwo idẹ. Nítorí-èyi, Olúwa ti pàṣẹ fún mi pé kí ìwọ àti àwọn arákùnrinrẹ lọ sí ilé Lábánì, kí ẹ sì wá àwọn ìwé ìrántí nã, kí ẹ sì mú wọn wá sísàlẹ̀ níhin sínú ijù. Àti nísisìyí, kíyèsĩ i àwọn arákùnrin rẹ n kùn, wọ́n n wí pé ohun tí ó le ni èyí tí mo bèrè lọ́wọ́ wọn; ṣùgbọ́n kíyèsĩ i èmi kò bèrè rẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àṣẹ Olúwa. Nítorínã lọ, ọmọ mi, ìwọ yíò sì rí ojú rere lọ́dọ̀ Olúwa, nítorí tí ìwọ kò kùn. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, sọ fún bàbá mi: Èmi yíò lọ láti ṣe àwọn ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ, nítorí tí èmi mọ̀ wí pé Olúwa kì yíò pa àṣẹ fún àwọn ọmọ ènìyàn, bíkòṣe pé òun yíò pèsè ọ̀nà fún wọn pé kí wọ́n lè parí ohun nã èyí tí òun pa láṣẹ fún wọn. Ó sì ṣe nígbà tí bàbá mi ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ó mọ̀ wí pé mo ti jẹ́ alábùkún-fún lọ́dọ̀ Olúwa. Èmi, Nífáì, àti àwọn arákùnrin mi sì mú ìrìn-àjò wa ní ijù, pẹ̀lú àwọn àgọ́ wa, láti gòkè lọ sí ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù. Ó sì ṣe nígbà tí a ti gòkè lọ sí ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, èmi àti àwọn arákùnrin mi fi ọ̀rọ̀ lọ ara wa. A sì ṣẹ́ kèké—tani nínú wa ni kí ó lọ sí ilé Lábánì. Ó sì ṣe tí kèké mú Lámánì; Lámánì sì wọ inú ilé Lábánì lọ ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ bí ó ṣe jóko ní ilé rẹ̀. Ó sì bẽrè lọ́wọ́ Lábánì àwọn ìwé-ìrántí èyí tí a gbẹ́ sórí àwọn àwo idẹ, èyí tí ó ní ìtàn ìdílé bàbá mi nínú. Sì kíyèsĩ i, ó sì ṣe tí Lábánì bínú, ó sì tì í jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀; kì yíò sì jẹ́ kí ó gba àwọn ìwé-ìrántí nã. Nítoríti, ó sọ fún un: Kíyèsĩ i ìwọ jẹ́ ọlọ́ṣà, èmi yíò sì pa ọ́. Ṣùgbọ́n Lámánì sá kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì sọ àwọn ohun tí Lábánì ti ṣe, fún wa. A sì bẹ̀rẹ̀ sí kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, àwọn arákùnrin mi sì fẹ́ padà sí ọ̀dọ̀ bàbá mi nínú ijù. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i mo sọ fún wọn pé: Bí Olúwa ti mbẹ, àti bí àwa ti mbẹ, àwa kì yíò sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá wa nínú ijù títí àwa ó fi ṣe ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún wa parí. Nítorí-èyi, ẹ jẹ́ kí á ṣe òtítọ́ ní pípa àwọn òfin Olúwa mọ́; nítorínã ẹ jẹ́ kí á sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ ìní bàbá wa, nítorí ẹ kíyèsĩ i ó fi wúrà àti fàdákà sílẹ̀, àti oríṣiríṣi ọrọ̀. Gbogbo eleyĩ ni ó sì ṣe nítorí àwọn òfin Olúwa. Nítorí ó mọ̀ pé Jerúsálẹ́mù yíò di píparun, nítorí ti ìwà búburú àwọn ènìyàn nã. Nítorí kíyèsĩ i, wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ sílẹ̀. Nítorí-èyi bí bàbá mi bá gbé ní ilẹ̀ nã lẹ̀hìn tí a ti pàṣẹ fún un láti sá jáde kúrò ní ilẹ̀ nã, kíyèsĩ i, òun yíò ṣègbé pẹ̀lú. Nítorí-èyi, ó di dandan fún un láti sá jáde kúrò ní ilẹ́ nã. Sì kíyèsĩ i, ó jẹ́ ọgbọ́n nínú Ọlọ́run pé kí àwa gba àwọn ìwé-ìrántí wọ̀nyí, kí á lè ṣe ìtọ́jú èdè àwọn bàbá wa fún àwọn ọmọ wa; Àti pẹ̀lú kí àwa lè ṣe ìtọ́jú fún wọn, àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí a ti sọ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́, èyí tí a ti fi fún wọn nípasẹ̀ Ẹ̀mí àti agbára Ọlọ́run, láti ìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀, àní títí di àkókò lọ́wọ́lọ́wọ́ yĩ. Ó sì ṣe pé irú èdè báyĩ ni mo fi yí àwọn arákùnrin mi lọ́kànpadà, kí wọ́n lè ṣe òtítọ́ ní pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Ó sì ṣe tí a sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ ìní wa, a sì ṣa wúrà wa jọ; àti fàdákà wa, àti àwọn nkan oníyebíye wa. Lẹ́hìn tí a sì ti ṣa àwọn nkan wọ̀nyí jọ, a lọ sókè lẹ̃kejì sí ilé Lábánì. Ó sì ṣe tí a wọlé tọ Lábánì lọ, a sì bẽrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ó fún wa ní àwọn ìwé-ìrántí nã èyí tí a fín sórí àwọn àwo ìdẹ, fún èyí tí àwa yíò fún un ní wúrà wa, àti fàdákà wa, àti gbogbo àwọn nkan oníyebíye wa. Ó sì ṣe nígbà tí Lábánì rí ohun ìní wa, àti wí pé ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó ṣe ìfẹ́kúfẹ̃ sí i, tóbẹ̃ tí ó tì wá sóde, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti pa wá, kí ó lè gba ohun ìní wa. Ó sì ṣe tí a sá fún àwọn ìránṣẹ́ Lábánì, tí ó fi jẹ́ wí pé a ní láti fi ohun ìní wa sílẹ̀, ó sì bọ́ sí ọwọ́ Lábánì. Ó sì ṣe tí a sá sínú ijù, àwọn ìránṣẹ́ Lábánì kò sì bá wa, a sì fi ara wa pamọ́ nínú ihò àpáta kan. Ó sì ṣe tí Lámánì bínú sí mi, àti pẹ̀lú sí bàbá mi; bákan nã sì ni Lẹ́múẹ́lì, nítorí ó fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Lámánì. Nítorí-èyi Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ líle sí wa, àwa àbúrò wọn ọkùnrin, wọ́n sì lù wá àní pẹ̀lú ọ̀pá. Ó sì ṣe bí wọ́n ṣe n lù wá pẹ̀lú ọ̀pá, kíyèsĩ i, angẹ́lì Olúwa kan wá ó sì dúró níwájú wọn, ó sì wí fún wọn, wí pé: Èéṣe tí ẹ̀yin fi n lu àbúrò yín ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀pá? Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé Olúwa ti yàn án láti jẹ́ alákọ́so lórí yín, ó sì ṣe èyi nítorí àìṣedẽdé yín? Kíyèsĩ i ẹ̀yin yíò tún gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, Olúwa yíò sì fi Lábánì lée yín lọ́wọ́. Lẹ́hìn tí ángẹ́lì nã sì ti sọ̀rọ̀ sí wa, ó lọ kúrò. Lẹ́hìn tí ángẹ́lì nã sì ti lọ kúrò, Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì tún bẹ̀rẹ̀ sí kùn, wí pé: Báwo ni yíò ti ṣe é ṣe pé Olúwa yíò fi Lábánì lé wa lọ́wọ́? Kíyèsĩ i ó jẹ́ alágbára ọkùnrin, ó sì lè pàṣẹ fún ãdọ́ta, bẹ̃ni, àní ó lè pa ãdọ́ta; njẹ́ ẽṣe tí kò ní le pa wá? 4 Nífáì pa Lábánì gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa ó sì gba àwọn àwo idẹ nã nípa lílo àrékérekè—Sórámù yàn láti darapọ̀ mọ́ ìdílé Léhì nínú ijù. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí mo wí fún àwọn arákùnrin mi, wí pé: Ẹ jẹ́ kí á tún gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, ẹ sì jẹ́ kí á ṣe òtítọ́ ní pípa àwọn òfin Olúwa mọ́; nítorí ẹ kíyèsĩ i ó lágbára ju gbogbo ayé, njẹ́ ẽṣe tí kò leè lágbára ju Lábánì àti ãdọ́ta rẹ̀, bẹ̃ni, tàbí ju ẹgbẽgbẹ̀rún rẹ̀ pãpã? Nítorínã ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ; ẹ jẹ́ kí á ní ágbára tí ó dàbí ti Mósè; nítorí ó sọ̀rọ̀ nítọ́tọ́ sí omi Òkun Pupa wọ́n sì pínyà síhin àti sọ́hun, àwọn bàbá wa sì lã já, jáde ìgbèkun, lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Fáráò sì tẹ̀lé wọn wọ́n sì rì sínú omi Òkun Pupa. Wàyí ẹ kíyèsĩ i ẹ̀yin mọ̀ wí pé èyí jẹ́ òtítọ́; ẹ̀yin sì mọ̀ pẹ̀lú wí pé angẹ́lì kan ti sọ̀rọ̀ sí yín; ẽ ha ti se tí ẹ̀yin yíò tún siyèméjì? Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ; Olúwa lè gbà wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn bàbá wa, kí ósì pa Lábánì run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Égíptì. Nísisìyí nígbàtí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n ṣì n bínú síbẹ̀, wọ́n sì múra si láti kùn; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọ́n tẹ̀lé mi gòkè títí a fi dé ẹ̀hìn odi Jerúsálẹ́mù. Ó sì jẹ́ ní òru; mo sì mú kí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sẹ́hìn odi. Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti fi ara wọn pamọ́, èmi, Nífáì, pa-kọ́lọ́ sínú ìlú nlá nã mo sì lọ níhà ilé Lábánì. Ẹ̀mi sì n tọ́ mi, n kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ àwọn ohun èyí tí èmi ìbá ṣe. Bíótilẹ̀ríbẹ̃ mo tẹ̀ síwájú, bí mo sì ti súnmọ́ ilé Lábánì mo rí ọkùnrin kan, ó sì ti ṣubú sí ilẹ̀ níwájú mi, nítorí tí ó ti mu àmupara pẹ̀lú ọtí-wáínì. Nígbà tí mo sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mo ri wí pé Lábánì ni. Mo sì ṣàkíyèsí idà rẹ̀, mo sì fà á jáde kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; ẽkù rẹ̀ jẹ́ ti wúrà tí ó dá ṣáká, iṣẹ́ rẹ̀ sì dára lọ́pọ̀lọpọ̀, mo sì ri wí pé ojú idà rẹ̀ jẹ́ ti irin oníyebíye jùlọ. Ó sì ṣe Ẹ̀mí rọ̀ mí láti pa Lábánì; ṣùgbọ́n mo sọ nínú ọkàn mi: N kò ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀ nígbà-kũgbà rí. Mo sì súnrakì mo fẹ́ wí pé kí n máṣe pa á. Ẹ̀mí sì tún sọ fún mi: Kíyèsĩ i Olúwa ti jọ̀wọ́ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Bẹ̃ni, mo sì tún mọ̀ wí pé ó ti wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí tèmi; bẹ̃ni, òun kò sì fetí sí àwọn òfin Olúwa; ó sì ti gba ohun ìní wa lọ pẹ̀lú. Ó sì ṣe tí Ẹ̀mí tún sọ fún mi: Pa á, nítorí Olúwa ti jọ̀wọ́ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́; Kíyèsĩ i Olúwa yíò pa ènìyàn búburú láti lè mú àwọn èrò rere rẹ̀ jáde wá. Ó sàn kí ènìyàn kan ṣègbé ju kí orílẹ̀-èdè kan rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ kí wọ́n sì ṣègbé. Àti nísisìyí, nígbàtí èmi, Nífáì, ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, mo rántí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí o wí fún mi nínú ijù, wí pé: Níwọ̀n bí àwọn irú-ọmọ rẹ bá pa àwọn òfin mi mọ́, wọn yíò ṣe rere ní ilẹ̀ ìlérí nã. Bẹ̃ni, mo sì rò ó pẹ̀lú wí pé wọn kò le è pa àwọn òfin Olúwa mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Mósè, bí kò ṣe pé wọ́n bá ní òfin nã. Mo sì mọ̀ pẹ̀lú wí pé a fín òfin nã sórí àwọn àwo idẹ nã. Ẹ̀wẹ̀, mo mọ̀ wí pé Olúwa ti jọ̀wọ́ Lábánì lé mi lọ́wọ́ fún ìdí èyí—kí èmi lè gba àwọn ìwé ìrántí nã gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin rẹ̀. Nítorínã mo gba ohùn Ẹ̀mí gbọ́, mo sì mú Lábánì níbi irun orí, mo sì gé orí rẹ̀ kúrò pẹ̀lú idà òun tìkara rẹ̀. Lẹ́hìn tí mo sì ti gé orí rẹ̀ kúrò pẹ̀lú idà tirẹ̀, mo mú awọn ẹ̀wù Lábánì mo sì wọ̀ wọ́n sí ara tèmi; bẹ̃ni, àní kan èyí tí ó kéré jùlọ; mo sì gbé ìhámọ́ra rẹ̀ wọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ mi. Lẹ́hìn tí mo sì ti ṣe èyí, mo jáde lọ sí ibi àpótí ìṣura Lábánì. Bí mo sì ti n jáde lọ síhà ibi àpótí ìṣura Lábánì, kíyèsĩ i, mo rí ìránṣẹ́ Lábánì ẹni tí ó ní kọ́kọ́rọ́ ibi àpótí ìṣura nã lọ́wọ́. Mo sì pàṣẹ fún un ní ohùn Lábánì, pé kí ó lọ pẹ̀lú mi sínú ibi àpótí ìṣura. Ó sì ṣèbí ọ̀gá òun, Lábánì, ni mí, nítorí ó rí awọn ẹ̀wù àti idà tí mo sán mọ́ ẹ̀gbẹ́ mi pẹ̀lú. Ó sì bá mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn àgbàgbà àwọn Jũ, ó mọ̀ wí pé ọ̀gá òun, Lábánì, ti jáde ní òru pẹ̀lú wọn. Mo sì bá a sọ̀rọ̀ bí ẹni pé Lábánì ni. Mo sì tún wí fún un wí pé èmi yíò gbé àwọn ìfín, èyí tí ó wà lórí àwọn àwo idẹ, lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, tí wọ́n wà lẹ́hìn odi. Mo sì tun pàṣẹ fún un wí pé kí ó tẹ̀lé mi. Òun nã, nítorí tí ó rò wí pé mo n sọ̀rọ̀ nípa àwọn arákùnrin ìjọ onígbàgbọ́, àti wí pé nítọ́tọ́ ni mo jẹ́ Lábánì nì, ẹni tí mo ti pa, nítorí-èyi ó tẹ̀lé mi. Ó sì bá mi sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà nípa àwọn àgbàgbà àwọn Jũ, bí mo ṣe n jáde lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin mi, tí wọ́n wà lẹ́hìn odi. Ó sì ṣe nígbà tí Lámánì rí mi ó bẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀, bẹ̃ nã gẹ́gẹ́ sì ni Lẹ́múẹ́lì àti Sãmú. Wọ́n sì sá kúrò níwájú mi; nítorí wọ́n ṣèbí Lábánì ni, àti wí pé ó ti pa mí ó sì ti wá láti mú ẹ̀mí wọn kúrò pẹ̀lú. Ó sì ṣe tí mo ké sí wọn, wọ́n sì gbọ́ mi; nítorí-èyi wọ́n dẹ́kun sísá kúrò lọ́dọ̀ mi. Ó sì ṣe nígbà tí ìránṣẹ́ Lábánì rí àwọn arákùnrin mi ó bẹ̀rẹ̀ sí n gbọ̀n, ó sì ti fẹ́ sá kúrò níwájú mi kí ó sì padà sí ìlú nlá Jerúsálẹ́mù. Àti nísisìyí èmi, Nífáì, nítorítí mo jẹ́ ènìyàn tí ó tóbi ní ìnà sókè ènìyàn, àti pẹ̀lú nítorítí mo ti gba agbára púpọ̀ lọ́wọ́ Olúwa, nítorínã mo gbá ìránṣẹ́ Lábánì mú, mo sì dì í mú, kí ó má bá sá. Ó sì ṣe tí mo bá a sọ̀rọ̀, wí pé tí ó bá lè fetí sí ọ̀rọ̀ mi, bí Olúwa ti wà, tí èmi sì wà, àní bẹ̃ni bí òun bá fetí sí ọ̀rọ̀ wa, àwa yíò yọ̣́da ẹ̀mí rẹ̀. Mo sì wí fún un, àní pẹ̀lú ìbúra, wí pé kí ó máṣe bẹ̀rù; wí pé yíò di òmìnira bí àwa ṣe wà bí òun bá sọ̀kalẹ̀ sínú ijù pẹ̀lú wa. Mo sì tún sọ fún un, wí pé: Dájúdájú Olúwa ti pá láṣẹ fún wa láti ṣe ohun yĩ; njẹ́ àwa kì yíò sì ha ṣe ãpọn ní pípa àwọn òfin Olúwa mọ́? Nítorínã, bí ìwọ bá lè sọ̀kalẹ̀ sínú ijù sọ́dọ̀ bàbá mi ìwọ yíò ní àyè pẹ̀lú wa. Ó sì ṣe ti Sórámù sì ní ìgboyà nítorí àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo sọ. Nísisìyí Sórámù ni orúkọ ìránṣẹ́ nã; ó sì ṣe ìlérí wí pé òun yíò sọ̀kalẹ̀ sínú ijù sí ọ̀dọ̀ bàbá wa. Bẹ̃ni, ó sì ṣe ìbúra fún wa wí pé òun yíò dúró-lẹ́hìn pẹ̀lú wa láti ìgbà nã lọ. Nísisìyí àwa fẹ́ kí ó dúrólẹ́hìn pẹ̀lú wa fún ìdí èyí, kí àwọn Jũ má bá mọ̀ nípa sísá kúrò wa sínú ijù, kí wọ́n má bá lépa wa kí wọ́n sì run wá. Ó sì ṣe nígbà tí Sórámù ti ṣe ìbúra fún wa, ìbẹ̀rùbojo wa dẹ́kun nípa rẹ̀. Ó sì ṣe tí a mú àwọn àwo idẹ nã àti ìránṣẹ́ Lábánì, a sì lọ kúrò sínu ijù, a sì rin ìrìn-àjò sí àgọ́ bàbá wa. 5 Sáráíà ráhùn sí Léhì—Àwọn méjẽjì yọ̀ lórí ìpadàbọ̀ àwọn ọmọkùnrin wọn—Wọ́n rú ẹbọ—Àwọn àwo idẹ nã ní àkọsílẹ̀ ti Mósè àti àwọn wòlĩ nínú—Àwọn àwo nã fihàn pé Léhì jẹ́ àtẹ̀lé Jósẹ́fù—Léhì sọtẹ́lẹ̀ nípa irú-ọmọ rẹ̀ àti nípa ìpamọ́ àwọn àwo nã. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.Ó sì ṣe lẹ́hìn tí a ti sọ̀kalẹ̀ sínú ijù sí ọ̀dọ̀ bàbá mi, kíyèsĩ i, ó kún fún ayọ̀, àti ìyá mi, Sáráíà pẹ̀lú, yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí nítọ́tọ́ ó ti ṣọ̀fọ̀ nítorí wa. Nítorí ó ti ṣèbí a ti ṣègbé nínú ijù; ó sì tún ti ráhùn sí bàbá mi, tó sọ fún un wí pé a-ríran ọkùnrin ni; ó wí pé: Kíyèsĩ i ìwọ ti tọ́ wa kúrò nínú ilẹ̀ ìní wa, àwọn ọmọkùnrin mi kò sì sí mọ́, a sì ṣègbé nínú ijù. Irú èdè báyĩ sì ni ìyá mi ti fi ráhùn sí bàbá mi. Ó sì ti ṣe tí bàbá mi sọ fún un, wí pé: Mo mọ̀ wí pé mo jẹ́ aríran ọkùnrin; nítorí bí kò bá ṣe pé èmi ti rí àwọn ohun Ọlọ́run nínú ìran èmi ìbá má mọ́ ọ́re Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmi ìbá ti dúró-lẹ́hìn ní Jerúsálẹ́mù, èmi ìbá sì ti ṣègbé pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, èmi ti gba ilẹ̀ ìlérí, nínú àwọn ohun èyí tí mo n yọ̀; bẹ̃ni, èmi sì mọ̀ wí pé Olúwa yíò gba àwọn ọmọkùnrin mi kúrò ní ọwọ́ Lábánì, yíò sì tún mú wọn sọ̀kalẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wa nínú ijù. Irú èdè báyĩ sì ni bàbá mi, Léhì, fi tu ìyá mi, Sáráíà, nínú nípa wa, ní àkókò tí a rin ìrìn-àjò nínú ijù sókè lọ sí ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, láti gba ìwé ìrántí àwọn Jũ. Nígbà tí a sì ti padà sí àgọ́ bàbá mi, kíyèsĩ i ayọ̀ wọn kún, a sì tu ìyá mi nínú. Ó sì sọ̀rọ̀, wí pé: Nísisìyí mo mọ̀ ní ìdánilójú wí pé Olúwa ti pá láṣẹ fún ọkọ mi láti sá sí inú ijù; bẹ̃ni, mo sì tún mọ̀ ní ìdánilójú wí pé Olúwa ti dãbò bò àwọn ọmọkùnrin mi, ó sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ Lábánì, ó sì ti fún wọn ní agbára nípa èyí tí wọ́n lè fi parí ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Irú èdè báyĩ ni ó sì sọ. Ó sì ṣe tí wọ́n sì yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì rú ẹbọ àti ẹbọ-ọrẹ sísun sí Olúwa; wọ́n sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Isráẹ́lì. Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Isráẹ́lì, bàbá mi, Léhì, gba àwọn ìwé ìrántí nã èyí tí a fín sórí àwọn àwo idẹ, ó sì yẹ̀ wọ́n wò láti ìbẹ̀rẹ̀. Ó sì ṣe àkíyèsí wí pé wọ́n ní àwọn ìwé márun ti Mósè nínú, èyí tí ó pèsè ìwé ìtàn ẹ̀dá ayé àti pẹ̀lú ti Ádámù àti Éfà, àwọn tí wọ́n jẹ́ òbí wa èkíní; Àti pẹ̀lú ìwé ìrántí àwọn Jũ láti àtètèkọ́ṣe, àní títí di ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sẹdẹkíàh, ọba Júdà; Àti pẹ̀lú àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ àwọn wòlĩ mímọ́, láti àtètèkọ́ṣe, àní títí di ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sẹdẹkíàh; àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ èyí tí a ti sọ láti ẹnu Jeremíàh. Ó sì ṣe pé bàbá mi, Léhì, tún rí ìtàn ìdílé àwọn bàbá rẹ̀ lórí àwọn àwo idẹ nã; nítorí-èyi ó mọ̀ wí pé òun jẹ́ àtẹ̀lé Jósẹ́fù; bẹ̃ ni, àní Jósẹ́fù nì, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ Jákọ́bù, ẹni tí a tà sí Égíptì, ẹni tí a sì pamọ́ nípa ọwọ́ Olúwa, kí ó lè ṣe ìpamọ́ bàbá rẹ̀, Jákọ́bù, àti gbogbo agbolé rẹ̀ kúrò nínú ṣíṣègbé pẹ̀lú ìyàn. A sì tọ́ wọn kúrò ní ìgbèkun àti kúrò ní ilẹ̀ Égíptì, nípa ọwọ́ Ọlọ́run kan nã ẹni tí ó ti pa wọ́n mọ́. Báyĩ sì ni bàbá mi, Léhì, ṣe mọ̀ nípa ìtàn ìdílé àwọn bàbá rẹ̀. Lábánì sì jẹ́ àtẹ̀lé Jósẹ́fù pẹ̀lú,nítorínã ni òun àti àwọn bàbá rẹ̀ ṣe tọ́jú àwọn ìwé ìrántí nã. Àti nísisìyí nígbà tí bàbá mi rí gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí, ó kún fún Ẹ̀mí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọtẹ́lẹ̀ nípa irú-ọmọ rẹ̀— Wí pé àwọn àwo idẹ wọ̀nyí yíò jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn tí ó jẹ́ ti irú-ọmọ rẹ̀. Nítorí-èyi, ó sọ wí pé àwọn àwo idẹ wọ̀nyí kì yíò ṣègbé láé; bẹ̃ni wọn kì yíò farasin ní ọ̀nàkọnà nípasẹ̀ àkókò. Ó sì sọtẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nípa irú-ọmọ rẹ̀. Ó sì ṣe tí títí di báyĩ èmi àti bàbá mi ti pa àwọn òfin nã mọ́ èyí tí Olúwa ti pàṣẹ fún wa. A sì ti gba àwọn ìwé ìrántí nã èyí tí Olúwa ti pàṣẹ fún wa, a sì ti yẹ̀ wọ́n wò fínni-fínni a sì ri wí pé wọ́n yẹ ní fífẹ́; bẹ̃ni, àní wọ́n jẹ́ iye nlá sí wa, níwọ̀n tí àwa fi lè ṣe ìtọ́jú àwọn òfin Olúwa fún àwọn ọmọ wa. Nítorí-èyi, ó jẹ́ ọgbọ́n nínú Olúwa wí pé kí á gbé wọn pẹ̀lú wa, bí a ṣe n rin ìrìn-àjò nínú ijù síhà ilẹ̀ ìlérí. 6 Nífáì kọ nípa àwọn ohun Ọlọ́run—Èrò Nífáì ni láti yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà láti wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ábráhámù kí a sì gbà wọ́n là. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kò kọ ìtàn ìdílé àwọn bàbá mi ni apá ìwé ìrántí mi yĩ; bẹ̃ni èmi kì yíò kọ ọ́ nígbà-kũgbà lẹ́hìn èyí sórí àwọn àwo wọ̀nyí tí èmi n kọ; nítorí ó ti wà nínú ìwé ìrántí èyí tí bàbá mi ti pamọ́; nítorí-èyi, èmi kò kọ ọ́ sínú iṣẹ́ yĩ. Nítorí ó tó mi láti sọ wí pé àwa jẹ́ àtẹ̀lé Jósẹ́fù. Kò sì jẹ́ ohunkóhun sí mi wí pé kí èmi ṣe àníyàn láti kọ ẹ̀kún ìwé ìtàn gbogbo àwọn nkan bàbá mi, nítorí wọn kò ṣe é kọ sórí àwọn àwo wọ̀nyí, nítorí mo fẹ́ ãyè kí èmi lè kọ nípa àwọn ohun Ọlọ́run. Nítorí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrò mi ni kí èmi lè yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà láti wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ábráhámù, àti Ọlọ́run Ísãkì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù, kí a sì gbà wọ́n là. Nítorí-èyi, àwọn ohun èyí tí ó ṣe ìfẹ́ ti ayé èmi kò kọ, ṣùgbọ́n àwọn ohun èyí tí ó ṣé ìfẹ́ ti Ọlọ́run ati si awọn wọ̣́nnì tí kĩ ṣe ti ayé. Nítorí-èyi, èmi yíò pa àṣẹ fún irú-ọmọ mi, pé àwọn kò gbọ́dọ̀ fi ãyè gba àwọn ohun tí kò ní iye sí àwọn ọmọ ènìyàn lórí àwọn àwo wọ̀nyí. 7 Àwọn ọmọkùnrin Léhì padà sí Jerúsálẹ́mù wọ́n sì pe Íṣmáẹ́lì àti agbolé rẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ wọn ní ìrìn àjò wọn—Lámánì àti àwọn míràn ṣọ̀tẹ̀—Nífáì gba àwọn arákùnrin rẹ̀ níyànjú láti ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa—Wọ́n dì í pẹ̀lú okùn wọ́n sì pèrò ìparun rẹ̀—Ó di òmìnira nípa agbára ìgbàgbọ́—Àwọn arákùnrin rẹ̀ tọrọ ìdáríjì—Léhì àti ọ̀wọ́ rẹ̀ rú ẹbọ àti ẹbọ-ọrẹ sísun. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.Àti nísisìyí èmi fẹ́ kí ẹ̀yin lè mọ̀ wí pé lẹ́hìn tí bàbá mi, Léhì, ti fi òpin sí àsọtẹ́lè nípa irú-ọmọ rẹ̀, ó ṣe tí Olúwa tún wí fún un, wí pé kò tọ́ fún un, Léhì, pé kí ó mú ìdílé rẹ̀ nìkan lọ sínú ijù; ṣùgbọ́n pé kí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ gbé àwọn ọmọbìnrin ní aya, kí wọn lè bímọ sí Olúwa ní ilẹ̀ ìlèrí. Ó sì ṣe tí Olúwa pàṣẹ fún un pé kí èmi, Nífáì, àti àwọn arákùnrin mi, tún padà sí ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, kí a sì mú Íṣmáẹ́lì àti ìdílé rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ wá sí ijù. Ósì ṣe tí èmi, Nífáì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi, tún jáde lọ sínú ijù láti gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ó sì ṣe tí a gòkè lọ sí ile Íṣmáẹ́lì, a sì rí ojúrere gbà níwájú Íṣmáẹ́lì tóbẹ̃ tí a sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un. Ó sì ṣe tí Olúwa mú ọkàn Íṣmáẹ́lì rọ̀, àti agbolé rẹ̀ pẹ̀lú, tóbẹ̃ tí wọ́n rin ìrìn-àjò wọn sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú wa sínú ijù sí àgọ́ bàbá wa. Ó sì ṣe bí a ṣe n rìn nínú ijù, kíyèsĩ Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì, àti méjì nínú àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì, àti àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì méjì àti àwọn ìdílé wọn, ṣọ̀tẹ̀ sí wa; bẹ̃ni sí èmi, Nífáì, àti Sãmú, àti bàbá wọn, Íṣmáẹ́lì, àti aya rẹ̀, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ míràn. Ó sì ṣe nínú ọ̀tẹ́ èyí tí, wọ́n fẹ́ láti padà sí ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù. Àti nísisìyí èmi, Nífáì, nítorí tí mo kẹ́dùn nítorí líle ọkàn wọn, nítorínã mo wí fún wọn, wí pé, bẹ̃ni, àní sí Lámánì àti sí Lẹ́múẹ́lì: Kíyèsĩ i ẹ̀yin jẹ́ ẹ̀gbọ́n mi, báwo ni tí ẹ̀yin sì ṣe le báyĩ ní ọkàn yín, tí ẹ sì fọ́jú ní inú yín, tí ẹ̀yin fẹ́ kí èmi, àbúrò yín, sọ̀rọ̀ sí yín, bẹ̃ni, kí èmi sì gbé àpẹrẹ kalẹ̀ fún yín? Báwo ni tí ẹ̀yin kò fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Olúwa? Báwo ni tí ẹ̀yin ti gbàgbé pé ẹ̀yin ti rí ángẹ́lì Olúwa kan? Bẹ̃ni, báwo sì ni tí ẹ̀yin ti gbàgbé àwọn ohun nlá tí Olúwa ti ṣe fún wa, ní gbígbà wá kúrò lọ́wọ́ Lábánì, àti pẹ̀lú tí àwa fi rí ìwé ìrántí nã gbà. Bẹ̃ni, báwo sì ni tí ẹ̀yin ti gbàgbé pé Olúwa lè ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, fún àwọn ọmọ ènìyàn, bí ó bá ṣe pé wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Nítorí-èyi, ẹ jẹ́ kí á jẹ́ olóotọ́ sí i. Bí ó bá sì ṣe pé àwa jẹ́ olóotọ́ sí i, àwa yíò rí ilẹ̀ ìlérí gbà; ẹ̀yin yíò sì mọ̀ ní ìgbà kan tí nbọ̀ pé ọ̀rọ̀ Olúwa yíò dí mímú ṣẹ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù; nítorí gbogbo ohun tí Olúwa ti sọ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù ni gbọdọ̀ di mímú ṣe. Nítorí kíyèsĩ i, Ẹ̀mí Olúwa yíò dáwọ́ dúró láìpẹ́ láti máa bá wọn wọ̀jà; nítorí kíyèsĩ i, wọ́n ti ṣa àwọn wòlĩ tì, Jeremíàh ni wọ́n sì ti jù sí inú túbú. Wọ́n sì ti wá ọ̀nà láti mú ẹ̀mi bàbá mi kúrò, tóbẹ̃ tí wọ́n ti lé e jáde ní ilẹ̀ nã. Nísisìyí kíyèsĩ i, mo sọ fún yín pé bí ẹ̀yin bá padà sí Jerúsálẹ́mù ẹ̀yin nã yíò ṣègbé pẹ̀lú wọn. Àti nísisìyí, bí ẹ̀yin bá ní yíyàn, ẹ gòkè lọ sí ilẹ̀ nã, kí ẹ sì rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, wí pé bí ẹ̀yin bá lọ ẹ̀yin yíò ṣègbé pẹ̀lú; nítorí báyĩ ni Ẹ̀mí Olúwa rọ̀ mí pé kí èmi kí ó sọ. Ó sì ṣe nígbà tí èmi, Nífáì, ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí àwọn arákùnrin mi, wọ́n bínú sí mi.Ó sì ṣe tí wọ́n gbá mi mú, nítorí kíyèsĩ i, wọ́n bínú lọ́pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì dì mí pẹ̀lú okùn, nítorí wọ́n wá láti mú ẹ̀mí mi kúrò, kí wọ́n lè fi mí sílẹ̀ sínú ijù kí àwọn ẹhànnà ẹranko lè pa mí jẹ. Ṣùgbọ́n ó ṣe tí mo gbàdúrà sí Olúwa, wípé: A! Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ mí tí nbẹ nínú rẹ, njẹ́ ìwọ yíò gbà mí lọ́wọ́ àwọn arákùnrin mi; bẹ̃ni, àní kí o fún mi ní agbára kí èmi lè já àwọn èdídì wọ̀nyí èyí tí a fi dì mí. Ó sì ṣe nígbà tí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kíyèsĩ i, àwọn èdídì nã túsílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀ mi, mo sì dúró níwájú àwọn arákùnrin mi, mo sì tún sọ̀rọ̀ sí wọn. Ó sì ṣe tí wọ́n tún bínú sí mi, wọ́n sì wá ọ̀nà láti gbá mi mú; sùgbọ́n kíyèsĩ i, ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì, bẹ̃ni, àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú, àti ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì, ṣìpẹ̀ sí àwọn arákùnrin mi, tóbẹ̃ tí wọ́n mú ọkàn wọn rọ̀; wọ́n sì dẹ́kun lílépa láti mú ẹ̀mí mi kúrò. Ó sì ṣe tí wọ́n kún fún ìbànújẹ́, nítorí ìwà búburú wọn, tóbẹ̃ tí wọ́n tẹríba níwájú mi, wọ́n sì ṣìpẹ̀ sí mi pé kí èmi kí ó dáríjì wọn fún ohun tí wọ́n ti ṣe sí mi. Ó sì ṣe tí mo dáríjì wọ́n ní ìfinúhàn, gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe, mo sì gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wọn fún ìdáríjì. Ó sì ṣe tí wọ́n ṣe bẹ̃. Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti gbàdúrà tán sí Olúwa a tún rin ìrìn-àjò wa síhà àgọ́ bàbá wa. Ó sì ṣe tí a sọ̀kalẹ̀ sí àgọ́ bàbá mi. Lẹ́hìn tí èmi àti àwọn arákùnrin mi àti gbogbo ilé Íṣmáẹ́lì sì ti sọ̀kalẹ̀ sí àgọ́ baba mi, wọ́n ṣe ọpẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run wọn; wọ́n sì rú ẹbọ àti ẹbọ-ọrẹ sísun sí i. 8 Léhì rí ìran igi ìyè—Ó jẹ nínú èso rẹ̀ ó sì fẹ́ kí ìdílé òun ṣe bẹ̃gẹ́gẹ́—Ó rí ọ̀pá irin kan, ọ̀nà híhá àti tọ́ró kan, àti òkùnkùn biribiri tí ó bò ènìyàn—Sáráíà, Nífáì, àti Sãmú jẹ nínú èso nã, ṣùgbọ́n Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì kọ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa. Ósì ṣe tí a ti kó onírúurú irúgbìn oríṣiríṣi jọ lákọ́pọ̀, àti ti oríṣiríṣi wóró irúgbìn, àti ti oríṣiríṣi irúgbìn èso pẹ̀lú. Ó sì ṣe nígbà tí bàbá mi dúrólẹ́hìn nínú ijù ó wí fún wa, wí pé: Kíyèsĩ i, mo ti lá àlá kan, tàbí ní ọ̀nà míràn, mo ti rí ìran kan. Sì kíyèsĩ i, nítorí ohun tí mo ti rí, mo ní ìdí láti yọ̀ nínú Olúwa nítorí ti Nífáì àti Sãmú pẹ̀lú; nítorí tí mo ní ìdí láti rò pé àwọn, àti púpọ̀ nínú irú-ọmọ wọn pẹ̀lú, ni a ó gbàlà. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì, mo bẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí yín; nítorí kíyèsĩ i, mo rò pé mo ri nínú àlá mi, ijù kan tí ó ṣókùnkùn tí ó sì binújẹ́. Ó sì ṣe tí mo rí ọkùnrin kan, ó sì wọ ẹ̀wù funfun kan, ó sì wá dúró níwájú mi. Ó sì ṣe tí ó sọ̀rọ̀ sí mi, ó sì pè mí kí n tẹ̀lé òun. Ó sì ṣe bí mo ṣe n tẹ̀lé e mo rí ara mi pé mo wá nínú ahoro kan tí ó ṣókùnkùn tí ó sì binújẹ́. Lẹ́hìn tí mo sì ti rin ìrìn-àjò fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí nínúòkùnkùn, mo bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Olúwa wí pé kí ó ní ãnú lórí mi, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrọnú ãnú rẹ̀. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí mo ti gbàdúrà sí Olúwa mo rí pápá kan tí ó tóbi tí ó sì gbọ́rò. Ó sì ṣe tí mo rí igi kan, èso èyí tí o yẹ ní fífẹ́ láti mú inú ẹni dùn. Ó sì ṣe tí mo jáde lọ mo sì jẹ nínú èso rẹ̀; mo sì ri wí pé ó dùn rékọjá, ju gbogbo ohun tí mo ti tọ́wò rí. Bẹ̃ni, mo sì ri wí pé èso rẹ̀ jẹ́ funfun, tí ó tayọ gbogbo fífunfun tí mo ti rí rí. Bí mo sì ti jẹ nínú èso rẹ̀ ó fi ayọ̀ nlá tí ó rékọjá kún ọkàn mi; nítorínã, mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ìfẹ́ wí pé kí ìdílé mi kí ó jẹ nínú rẹ̀ pẹ̀lú; nítorí mo mọ̀ wí pé ó yẹ ní fífẹ́ ju gbogbo èso míràn. Bí mo sì ti gbé ojú mi yíká kãkiri pé bóyá mo lè wá ìdílé mi rí pẹ̀lú, mo rí odò omi kan, ó sì n ṣàn lọ, ó sì wà nítòsí igi èyí tí mọ̀ n jẹ èso rẹ̀. Mo sì wò láti rí ibi tí ó ti wá; mo sì rí orísun rẹ̀ níwájú díẹ̀; níbi orísun nã mo sì rí ìyá rẹ Sáráíà, àti Sãmú, àti Nífáì; wọ́n sì dúró bí pé wọn kò mọ́ ibi tí wọn yíò lọ. Ó sì ṣe mo juwọ́ sí wọn; mo sì tún sọ fún wọn pẹ̀lú ohùn kíkan wí pé kí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí wọ́n jẹ nínú èso nã, èyí tí ó yẹ ní fífẹ́ ju gbogbo èso míràn. Ó sì ṣe tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ mi tí wọ́n sì jẹ nínú èso nã pẹ̀lú. Ó sì ṣe tí mo ní ìfẹ́ wí pé kí Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì wá jẹ nínú èso nã pẹ̀lú; nítorínã, mo gbé ojú mi síhà orísun odò nã, wí pé bóyá mo lè rí wọn. Ó sì ṣe tí mo rí wọn, ṣùgbọ́n wọn kò wá sí ọ̀dọ̀ mi kí wọ́n sì jẹ nínú èso nã. Mo sì rí ọ̀pá irin kan, ó sì gùn lọ lẹ́gbẹ̃ bèbè odò nã, ó sì gùn dé ibi igi ní ẹ̀bá èyí tí mo dúró. Mo sì tún rí ọ̀nà híhá àti tọ́ró kan, èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̃ ọ̀pá irin nã, títí fi dé ibi igi ẹ̀bá èyí tí mo dúró; ó sì gùn kọjá orísun nã pẹ̀lú, títí dé pápá kan tí ó tóbi tí ó sì gbọ́rò, bí ẹni pé ó jẹ́ ayé kan. Mo sì rí àjọ àìníye àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ èyí tí ó n tẹ̀ síwájú, kí wọ́n lè dé ọ̀nà nã èyí tí ó lọ sí ibi igi ni ẹ̀bá èyí tí mo dúró. Ó sì ṣe tí wọ́n jáde wá, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ọ̀nà èyí tí ó lọ sí ibi igi nã. Ó sì ṣe tí òkùnkùn biribiri yọ jáde; bẹ̃ni, àní òkùnkùn biribiri nlá lọ́pọ̀lọpọ̀, tóbẹ̃ tí àwọn tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ọ̀nà nã ṣìnà, tí wọ́n ṣáko kúrò tí wọ́n sì sọnù. Ó sì ṣe tí mo rí àwọn míràn tí wọ́n n tẹ̀ síwájú, wọ́n sì jáde wá wọ́n sì di ìdí ọ̀pá irin nã mú; wọ́n sì tẹ̀ síwájú lãrín òkùnkùn biribiri nã, wọ́n rọ̀ mọ́ ọ̀pá irin nã, àní títí tí wọ́n fi jáde wá tí wọ́n sì jẹ nínú èso igi nã. Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti jẹ nínú èso igi nã wọ́n gbé ojú wọn yíkãkiri bí ẹni pé wọ́n n tijú. Mo sì tún gbé ojú mi yíká kãkiri, mo sì ṣàkíyèsí ilé nlá kan tí o sì gbọ́rò ní òdì kejì odò omi nã; ó sì dàbí pé ó dúró ní òfúrufú, tí ó ga lórí ilẹ̀. Ó sì kún fún ènìyàn, àti ogbó àti ọ̀dọ́, àti ọkùnrin àti obìnrin; ìmúra wọn sì dára lọ́pọ̀lọpọ̀; wọ́n sì wà ní ìṣesí fífi ṣe ẹlẹ́yààti nína ìka ọwọ́ síhà àwọn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì n jẹ èso nã. Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti tọ́ èso nã wò ojú tì wọ́n, nítorí àwọn tí ó n kẹ́gàn wọn; wọ́n sì ṣáko lọ sínú àwọn ọ̀nà tí a kà lẽwọ̀ wọ́n sì sọnù. Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kò sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ bàbá mi. Ṣùgbọ́n, kí n lè ké ìwé mi kúrú, kíyèsĩ i, ó rí ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn míràn tí wọ́n n tẹ̀ síwájú, wọ́n sì wá wọ́n sì di ìdí ọ̀pá irin nã mú; wọ́n sì tẹ̀ síwájú lọ́nà wọn, wọ́n n di ọ̀pá irin nã mú ṣinṣin títí lọ, títí wọ́n fi jáde wá tí wọ́n wólulẹ̀ tí wọ́n sì jẹ nínú èso igi nã. Ó sì tún rí ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn míràn tí wọ́n n fọwọ́wá ọ̀nà wọn síhà ilé nlá tí ó sì gbọ́rò nì. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó rì sínú omi nínú ibú orísun nã; ọ̀pọ̀ ni ó sì sọnù tí kò rí mọ́, tí wọ́n n ṣáko ní awọn ọ̀nà tí ó ṣàjèjì. Ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn nã sì pọ̀ tí ó wọ inú ilé tí ó ṣàjèjì nì. Lẹ́hìn tí wọ́n sì wọ inú ilé nì wọ́n na ìka ọwọ́ ẹ̀gàn sí èmi àti àwọn tí ó n jẹ nínú èso nã pẹ̀lú; ṣùgbọ́n àwa kò kíyèsĩ wọn. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ bàbá mi: Nítorí gbogbo àwọn tí ó kíyèsĩ wọn ni ó ti ṣáko. Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì kò sì jẹ nínú èso nã, bẹ̃ni bàbá mi sọ. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí bàbá mi ti sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ àlá tàbí ìran rẹ̀, èyí tí ó pọ̀, ó sọ fún wa, nítorí àwọn ohun wọ̀nyí tí ó rí nínú ìran, ó bẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì; bẹ̃ni, ó bẹ̀rù kí a máṣe ta wọ́n nù kúrò níwájú Olúwa. Ó sì gbà wọ́n níyànjú nígbà nã pẹ̀lú gbogbo ìmọ̀ òbí tí ó ṣàníyàn, pé kí wọ́n fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, pé bóyá Olúwa yíò ni ãnú sí wọn, tí kì yíò sì ta wọ́n nù; bẹ̃ni, bàbá mi wãsù sí wọn. Lẹ́hìn tí ó sì ti wãsù sí wọn, tí ó sì sọtẹ́lẹ̀ sí wọn pẹ̀lú nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun, o rọ̀ wọ́n láti pa òfin Olúwa mọ́; ó sì dẹ́kun sísọ̀rọ̀ sí wọn. 9 Nífáì ṣe ìwé ìrántí sí ọ̀nà méjì—À n pe ọ̀kọ̣́kan ní àwọn àwo ti Nífáì—Àwọn àwo nlá ní ìwé ìtàn ti ayé nínú; àwọn kékeré nĩ ṣe pẹ̀lú àwọn ohun mímọ́. Níwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa. Gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí sì ni bàbá mi rí, tí ó sì gbọ́, tí ó sì sọ, bí ó ṣe gbé nínú àgọ́, ní àfonífojì Lẹ́múẹ́lì, àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nlá sí i, èyí tí kò ṣe é kọ sórí àwọn àwo wọ̀nyí. Àti nísisìyí gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ nípa àwọn àwo wọ̀nyí, kíyèsĩ i wọn kì í ṣe àwọn àwo èyí tí mo ṣe kíkún ìwé ìtàn ti ìrántí àwọn ènìyàn mi sórí wọn; nítorí àwọn àwo èyí tí mo ṣe ìwé ìtàn kíkún àwọn ènìyàn mi sórí wọn ni mo ti fún ní orúkọ Nífáì; nítorí-èyi, à n pè wọ́n ní àwọn àwo ti Nífáì, ní àpètẹ̀lé orúkọ tèmi; àwọn àwo wọ̀nyí sì ni à n pè ní àwọn àwo ti Nífáì. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo ti gba àṣẹ lọ́wọ́ Olúwa pé kí èmi kí ó ṣe àwọn àwo wọ̀nyí, fún àkànṣe ète pé kí ìwé ìtàn tí a fín nípa ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ènìyàn mi le wà. Lórí àwọn àwo kejì ni kí a fín ìwé ìtàn ìjọba àwọn ọba sí, àti àwọn ogun àti ìjà àwọnènìyàn mi; nítorí-èyi àwọn àwo wọ̀nyí wà fún èyí tí ó pọ̀jù ní iṣẹ́ ìránṣẹ́ nã; àwọn àwo kejì sì wà fún èyí tí ó pọ̀jù ní ìjọba àwọn ọba àti àwọn ogun àti ìjà àwọn ènìyàn mi. Nítorí-èyi Olúwa ti pàṣẹ fún mi láti ṣe àwọn àwo wọ̀nyí fún ète òye nínú rẹ̀, ète èyí tí èmi kò mọ̀. Ṣùgbọ́n Olúwa mọ́ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀; nítorí-èyi, ó pèsè ọ̀nà láti ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ parí lãrín àwọn ọmọ ènìyàn; nítorí kíyèsĩ i, ó ní gbogbo agbára sí mímú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Báyĩ ni ó sì rí. Àmín. 10 Léhì sọtẹ́lẹ̀ pé àwọn Jũ ni a ó mú ní ìgbèkùn nípasẹ̀ àwọn ará Bábílọ́nì—Ó sọ nípa bíbọ̀ Messia kan, Olùgbàlà àti Olùràpadà lãrín àwọn Jũ—Léhì sọ pẹ̀lú nípa bíbọ̀ ẹni tí yíò rì Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run nã bọmi—Léhì sọ nípa ikú àti àjínde òkú ti Messia nã—Ó fi títúká àti kíkójọ Ísráẹ́lì wé igi ólífì—Nífáì sọ nípa Ọmọ Ọlọ́run, nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, àti nípa ṣíṣe òdodo. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí èmi, Nífáì tẹ̀ síwájú láti kọ ìwé ìtàn àwọn íṣe mi, àti ìjọba àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi sórí àwọn àwo wọ̀nyí; nítorí-èyi, láti tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìwé ìtàn tèmi, mo gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn ohun ti bàbá mi, àti ti àwọn arákùnrin mi pẹ̀lú. Nítorí kíyèsĩ i, ó ṣe lẹ́hìn tí bàbá mi ti parí sísọ àwọn ọ̀rọ̀ àlá rẹ̀, àti gbígbà wọ́n níyànjú sí ãpọn ní ohun gbogbo pẹ̀lú, ó wí fún wọn nípa àwọn Jũ— Wí pé lẹ́hìn tí a bá pa wọ́n run, àní Jerúsálẹ́mù ìlú nlá nì, tí a sì tí mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ìgbèkùn lọ sí Bábílọ́nì, gẹ́gẹ́ bí àkókò tí ó yẹ níti Olúwa, wọn yíò tún padà, bẹ̃ni, àní a ó mú wọn padà jáde ní ìgbèkun; lẹ́hìn tí a bá sì mú wọn padà jáde ní ìgbèkun wọn yíò tún gba ilẹ̀ ìní wọn. Bẹ̃ni, àní ní ẹgbẹ̀ta ọdún sí ìgbà tí bàbá mi kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wòlĩ kan ni Olúwa Ọlọ́run yíò gbé dìde lãrín àwọn Jũ—àní Messia kan, tàbí, ní ọ̀nà míràn, Olùgbàlà ayé. Ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú nípa àwọn wòlĩ, bí púpọ̀ ní iye wọn ti jẹ́rĩ sí àwọn ohun wọ̀nyí, nípa Messia yĩ, ẹni tí òun ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, tàbí Olùràpadà ayé yĩ. Nítorí-èyi, gbogbo aráyé wà ní ipò ìsọnù àti ti ìṣubú, wọn ó sì wà bẹ̃ láé àfi tí wọ́n bá gbíyèlé Olùràpadà yĩ. Ó sì wí nípa wòlĩ kan ẹni tí yíò wá ṣíwáju Messia nã, láti tún ọ̀nà Olúwa ṣe— Bẹ̃ni, àní òun yíò jáde lọ yíò sì kígbe ní ijù: Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ sì ṣe ojú-ọ̀nà rẹ̀ tọ́; nítorí ọ̀kan dúró lãrín yín ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀; òun sì lágbára jù mí lọ, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò yẹ láti tú. Púpọ̀ sì ni ohun tí bàbá mi sọ nípa nkan yĩ. Bàbá mi sì sọ wí pé yíò rìnibọmi ní Bẹtabárà, níkọjá Jordánì; ó sì sọ pẹ̀lú pé yíò rìnibọmi pẹ̀lú omi, àní wí pé yíò ṣe ìrìbọmi fun Messia nã pẹ̀lú omi. Àti lẹ́hìn tí ó bá ti ṣe ìrìbọmi fun Messia nã pẹ̀lú omi, yíò jẹ́wọ́ yíò sì jẹ́rĩ wí pé òun ti riỌ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run bọmi, ẹni tí yíò mú ẹ̀sẹ̀ ayé lọ. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí bàbá mi ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó sọ̀rọ̀ sí àwọn arákùnrin mi nípa ìhìn-rere èyí tí a ó wãsù lãrín àwọn Jũ, àti pẹ̀lú nípa rirẹhin àwọn Jũ nínú ìgbàgbọ́. Lẹ́hìn tí wọ́n bá ti pa Messia nã, ẹni tí yíò wá, lẹ́hìn tí a bá sì ti pa á òun yíò jínde kúrò nínú òkú, yíò sì fi ara rẹ̀ hàn, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, sí àwọn Kèfèrì. Bẹ̃ni, àní bàbá mi sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa àwọn Kèfèrí àti nípa ará ilé Ísráẹ́lì pẹ̀lú, wí pé wọn yíò rí bí igi ólífì, ẹ̀ka èyí tí a ó ṣẹ́ kúrò tí a ó sì túká sórí gbogbo ojú-ilẹ̀ àgbáyé. Nítorí-èyi, ó sọ pé ó ṣe dandan pé kí a tọ́ wa pẹ̀lú ọkàn kan sínú ilẹ̀ ìlérí sí mímú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ, wípé a ó tú wa ká sórí gbogbo ojú-ilẹ̀ àgbáyé. Lẹ́hìn tí a bá sì ti tú ará ilé Ísráẹ́lì ká a ó tún kó wọn jọ; tàbí, ní ṣókí, lẹ́hìn tí àwọn Kèfèrí bá ti gba ẹ̀kún Ìhìn-rere ẹká àdánidá igi ólífi nã, tàbí àwọn ìyókù ará ilé Ísráẹ́lì, ni a ó lọ́ sínú igi nã, tàbí wá sí ìmọ̀ Messia òtítọ́, Olúwa wọn àti Olùràpadà wọn. Irú èdè báyĩ sì ni bàbá mi fi sọtẹ́lẹ̀ tí ó sì sọ̀rọ̀ sí àwọn arákùnrin mi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun sí i pẹ̀lú èyí tí èmi kò kọ sínú ìwé yĩ; nítorí ó ti kọ púpọ̀ tí ó jẹ́ yíyẹ fún mi nínú ìwé mi míràn. Gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí, èyí tí mo ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ni a sì ṣe nígbà tí bàbá mi n gbé nínú àgọ́, ní àfonífojì Lẹ́múẹ́lì. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí èmi, Nífáì, tí mo ti gbọ́ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ bàbá mi, nípa àwọn ohun tí ó rí nínú ìran, àti pẹ̀lú àwọn ohun tí ó sọ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́, agbára èyí tí ó gbà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run—Ọmọ Ọlọ́run nã sì jẹ́ Messia tí yíò wá—èmi, Nífáì, nífẹ pẹ̀lú pé kí èmi lè rí, kí n gbọ́, kí n sì mọ̀ nípa àwọn nkan wọ̀nyí, nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí ó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run fún gbogbo àwọn tí ó bá wá a lójúméjẽjì, gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà àtijọ́ àti bí ti ìgbà tí yíò fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn. Nítorí ó jẹ́ ọ̀kan nã ní áná, ní óní, àti títí láé; a sì ti pèsè ọ̀nà fún gbogbo ènìyàn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wa, bí ó bá ṣe pé wọ́n ronúpìwàdà tí wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nítorí ẹni tí ó bá wá lójúméjẽjì yíò rí; ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run ni a ó sì fihàn sí wọn, nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́, ní ìgbà yí gẹ́gẹ́ bí ìgbà àtijọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà àtijọ́ bí ìgbà tí nbọ; nítorí-èyi ipa ọ̀nà Olúwa jẹ́ ọ̀nà àìyípadà ayérayé kan. Nítorínã rántí, A! ọmọ ènìyàn, fún gbogbo ìṣe rẹ a o mú ọ wá sínú ìdájọ́. Nítorí-èyi, bí ìwọ bá ti wá láti ṣe búburú ní ìgbà ayé-ìdánwò rẹ, njẹ́ a ó rí ọ ní àìmọ́ níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run; ohun àìmọ́ kan kò sì lè gbé pẹ̀lú Ọlọ́run; nítorí-èyi a ó ta ọ́ nù títí láé. Ẹ̀mí Mímọ́ sì fún mi ní àṣẹ pe ki n sọ àwọn nkan wọ̀nyí, kí n má si ṣe sẹ́ wọn. 11 Nífáì rí Ẹ̀mí Olúwa, a sì fi igi ìyè hàn á ní ojúran—Ó rí ìyá ỌmọỌlọ́run ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìrẹ-ara-sílẹ̀ ti Ọlọ́run—Ó rí ìrìbọmi, iṣẹ́ ìránṣẹ́, áti ìkànmọ́ àgbélèbú ti Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run—Ó rí ìpè àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti àwọn Àpóstélì Méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn pẹ̀lú. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa. Nítorí ó sì ṣe lẹ́hìn tí mo ti fẹ́ láti mọ́ àwọn ohun tí bàbá mi ti rí, tí mo sì gbàgbọ́ wípé Olúwa lè sọ wọ́n di mímọ̀ fún mi, bí mo ṣe jóko tí mọ̀ nrò nínú ọkàn mi, a mú mi lọ nínú Ẹ̀mí Olúwa, bẹ̃ni, sí òkè gíga gan-an, èyí tí èmi kò tí ì rí rí, orí èyí tí èmi kò sì tí tẹ̀ rí. Ẹ̀mí nã sì sọ fún mi: Kíyèsĩ, kíni ìwọ nfẹ́? Mo sì wípé: Mo fẹ́ láti rí àwọn ohun tí bàbá mi rí. Ẹ̀mí nã sì sọ fún mi: Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé bàbá rẹ rí igi èyí tí ó ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Mo sì wípé: Bẹ̃ni, ìwọ mọ̀ wípé mo gba gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ bàbá mi gbọ́. Nígbàtí mo sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Ẹ̀mí nã kígbe pẹ̀lú ohùn rara, wípé: Hòsánnà sí Olúwa, Ọlọ́run ẹnití-ó-gá-jùlọ; nítorítí ó jẹ́ Ọlọ́run lórí gbogbo ayé, bẹ̃ni, àní ga ju ohun gbogbo lọ. Alábùkún-fún sì ni ìwọ, Nífáì, nítorítí ìwọ gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run ẹnití-ó-gá-jùlọ; Nítorínã ìwọ yíò rí àwọn ohun tí ìwọ nfẹ́. Sì kíyèsĩ i nkàn yí ni a ó fi fún ọ fún àmì, pé lẹ́hìn tí ìwọ bá ti rí igi èyí tí ó so èso èyí tí bàbá rẹ tọ́wò, ìwọ yíò rí ọkùnrin kan pẹ̀lú tí ó nsọ̀kalẹ̀ jáde láti ọ̀run, òun sì ni ìwọ yíò ṣe lẹ́rĩ; lẹ́hìn tí ìwọ bá sì ti jẹ́rĩ rẹ̀ ìwọ yíò jẹ́rĩ pe ó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run. Ó sì ṣe tí Ẹ̀mí ná à wí fún mi: Wò ó! Mo si wò ó, mo sì kíyèsĩ igi kan; ó sì dàbí igi èyítí bàbá mi ti rí; ẹwà rẹ̀ sì rékọjá jìnà, bẹ̃ni, tayọ gbogbo ẹwà; funfun rẹ̀ sì tayọ funfun ìrì dídì tí afẹ́fẹ́ kójọ. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí mo ti rí igi nã, mo wí fún Ẹ̀mí nã: Mo kíyèsĩ pé ìwọ ti fi igi èyítí ó níye lórí ga ju gbogbo ohun lọ hàn mí. Ó sì wí fún mi: Kíni ìwọ fẹ́? Mo sì wí fún un: Láti mọ́ ìtumọ̀ èyínã—nítorí mo bá a sọ̀rọ̀ bí ènìyàn ṣe nsọ̀rọ̀; nítorí mo kíyèsĩ i wípé ó wà ní ìwo ti ènìyàn; sùgbọ́n bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo mọ̀ wípé Ẹ̀mí Olúwa ni; ó sì bá mi sọ̀rọ̀ bí ènìyàn kan ṣe nbá òmíràn sọ̀rọ̀. Ó sì ṣe tí ó sọ fún mi: Wò ó! Mo sì wò bí ẹni pé kí n wò ó, èmi kò sì rí i; nítorí ó ti lọ kúrò níwájú mi. Ó sì ṣe tí mo wò tí mo sì rí ìlú-nlá Jerúsálẹ́mù nì, àti àwọn ìlú-nlá míràn pẹ̀lú. Mo sì rí ìlú-nlá Násárẹ́tì; ní ìlú-nlá Násárẹ́tì mo sì rí wúndíá kan, ó sì dára, ó sì funfun lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó sì ṣe tí mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀; angẹ́lì kan sì sọ̀kalẹ̀ ó sì dúró níwájú mi; ó sì wí fún mi: Nífáì, kíni ìwọ rí? Mo sì wí fún un: Wúndíá kan, tí ó lẹ́wà tí ó sì dára ju gbogbo àwọn wúndíá míràn lọ. Ó sì wí fún mi: Njẹ́ ìwọ mọ́ ìrẹ-ara-sílẹ̀ ti Ọlọ́run? Mo sì wí fún un: Mo mọ̀ wípé ó fẹ́ràn àwọn ọmọ rẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi kò mọ́ ìtúmọ̀ ohun gbogbo. Ó sì wí fún mi: Kíyèsĩ, wúndíá tí ìwọ rí nì jẹ́ ìyá Ọmọ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara. Ó sì ṣe tí mo rí tí a mú u lọ nínú Ẹ̀mí; lẹ́hìn tí a sì ti mú u lọ nínú Ẹ̀mí ní ìwọ̀n ìgbà díẹ̀, angẹ́lì ná à bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Wò ó! Mo sì wò mo sì tún kíyèsĩ wúndíá ná à, ó gbé ọmọ kan ní ọwọ́ rẹ̀. Angẹ́lì nã sì wí fún mi: Wo Ọ̀dọ́-àgùtan Ọlọ́run, bẹ̃ni, àní Ọmọ Bàbá Ayérayé! Njẹ́ ìwọ mọ́ ìtumọ̀ igi èyí tí bàbá rẹ rí? Mo sì dá a lóhùn wípé: Bẹ̃ni, ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, èyítí ó tan ara rẹ̀ ká lóde nínú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn; nítorínã, ó jẹ́ ohun ti o wuni ju gbogbo ohun lọ. Ó sì bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Bẹ̃ni, àti tí o ṣe inú dídùn jùlọ fún ọkàn. Lẹ́hìn tí ó sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó wí fún mi: Wò ó! Mo sì wò, mo sì rí Ọmọ Ọlọ́run tí ó n kãkiri lãrín àwọn ọmọ ènìyàn; mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n wolẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un. Ó sì ṣe tí mo rí wípé ọ̀pá irin nã, èyí tí bàbá mi ti rí, jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ó tọ́ni sí orísun omi ìyè, tàbí sí igi ìyè; omi èyí tí ó jẹ́ àpẹrẹ ìfẹ́ Ọlọ́run; mo si tún rí i wípé igi ìyè nã jẹ́ àpẹrẹ ìfẹ́ Ọlọ́run. Angẹ́lì ná à sì tún wí fún mi: Wò kí o sì ri ìrẹ-ara-sílẹ̀ Ọlọ́run! Mo sì wò mo sì rí Olùràpadà ayé, ẹni tí bàbá mi ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀; mo sì tún rí wòlĩ nã ẹni tí yíò tún ọ̀nà ṣe ṣíwájú rẹ̀. Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run ná à sì jáde lọ a sì r ì i bọmi nípa ọwọ́ rẹ̀; Lẹ́hìn tí a sì rìbọmi rẹ̀, mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, ó sì bà sórí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà. Mo sì rí i wípé ó jáde lọ ó n ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn, ní agbára àti ògo nlá; ọ̀pọ̀ ènìyàn sì jùmọ̀ péjọ láti gbọ́ ọ; mo sì rí i wípé wọ́n lée jáde kúrò lãrín wọn. Mo sì tún rí àwọn méjìlá míràn tí wọ́n ntẹ̀lé e. Ó sì ṣe tí a mú wọn lọ nínú Ẹ̀mí kúrò níwájú mi, èmi kò sì rí wọn. Ó sì ṣe tí ángẹ́li ná à tún bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Wò ó! Mo sì wò, mo sì kíyèsí àwọn ọ̀run tí wọ́n tún ṣí sílẹ̀, mo sì rí àwọn ángẹ́lì tí wọ́n nsọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ọmọ ènìyàn; wọ́n sì ṣe isẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn. Ó sì tún bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Wò ó! Mo sì wò, mo sì kíyèsí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run tí ó nkãkiri lãrín àwọn ọmọ ènìyàn. Mo sì kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n nṣàìsàn, tí a sì pọ́n-lójú pẹ̀lú onírũrú àrùn gbogbo, àti pẹ̀lú àwọn èṣù àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́; angẹ́lì nã sì sọ, ó sì fi gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí hàn mí. Wọ́n sì rí ìwòsàn nípasẹ̀ agbára Ọ̀dọ́àgùtàn Ọlọ́run; àwọn èṣù àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ni a sì lé jáde. Ó sì ṣe tí angẹ́lì ná à tún bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Wò ó! Mo sì wò mo sì kíyèsí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, tí àwọn ènìyàn mú u; bẹ̃ni, Ọmọ Ọlọ́run títí ayé ni a dáléjọ́ nípa ayé; mo sì rí mo sì jẹ́rĩ. Èmi, Nífáì, sì ri i tí a gbé e sókè sórí àgbélèbú tí a sì pa á fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ayé. Lẹ́hìn tí a sì ti pa á, mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn ayé, tí wọ́n jùmọ̀ péjọ lati dojú ìjà kọ àwọn àpóstélìỌ̀dọ́-àgùtàn; nítorí báyĩ ni angẹ́lì Olúwa pe àwọn méjìlá nã. Ọ̀pọ̀ ènìyan ayé sì jùmọ̀ péjọ; mo sì kíyèsí pé wọ́n wà nínú ilé kan tí ó tóbi tí ó sì gbọ́rò, tí o dàbí ilé èyí tí bàbá mi rí. Angẹ́lì Olúwa ná à sì tún bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Kíyèsí ayé àti ọgbọ́n inú rẹ̀; bẹ̃ni, kíyèsĩ ará ilé Isráẹ́lì ti jùmọ̀ péjọ láti dojú ìjà kọ àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn. Ó sì ṣe tí mo rí tí mo sì jẹ́rĩ, pé ilé tí ó tóbi tí ó sì gbọ́rò nã jẹ́ ìgbéraga ayé; ó sì wó, wíwó rẹ̀ sì pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Angẹ́lì Olúwa ná à sì tún bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Báyĩ ni ìparun gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè àti ènìyàn yíò rí, tí yíò dojú ìjà kọ àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn. 12 Nífáì rí ilẹ̀ ìlérí nínú ìran; ó rí òdodo, àìṣedẽdé, àti ìṣubú àwọn olùgbé rẹ̀; bíbọ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run lãrín wọn; bí àwọn Ọmọ-ẹ̀hìn méjẽjìlá àti àwọn Àpóstélì méjẽjìlá yíò ṣe ìdájọ́ fún Isráẹ́lì; àti ipò ẹlẹ́gbin àti elẽrí àwọn tí wọ́n rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa. Ó sí ṣe tí angẹ́lì ná à wí fún mi: Wò ó, sì kíyèsí irú-ọmọ rẹ, àti irú-ọmọ arákùnrin rẹ pẹ̀lú. Mo sì wò mo sì kíyèsí ilẹ̀ ìlérí ná à; mo sì kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, bẹ̃ni, àní bí ó ti rí ní iye, tí wọn pọ̀ bí iyanrìn òkun. Ó sì ṣe tí mo kíyèsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n kórajọ láti jagun, tí ọ̀kan ndojúkọ èkejì; mo sì kíyèsí ogun, àti ìdàgìrì ogun, àti ìpakúpa nlá pẹ̀lú idà lãrín àwọn ènìyan mi. Ó sì ṣe tí mo kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran tí ó rékọjá, nípasẹ̀ ọ̀nà àwọn ogun àti àwọn ìjà ní ilẹ̀ nã; mo sì kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá, bẹ̃ni, àní tí n kò ka iye wọn. Ó sì ṣe tí mo rí ìkũku ní ojú ilẹ̀ ìlérí; mo sì rí àwọn mọ̀nàmọ́ná, mo sì gbọ́ sísán àwọn àrá, àti ilẹ̀ rírì àti gbogbo onírurú àwọn ariwo rúdurùdu; mo sì rí ilẹ̀ àti àwọn àpáta, tí wọ́n s á n ; mo s ì r í àwọn ò k è gíga tí wọ́n sì nwó lulẹ̀; mo sì rí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aiyé, tí wọ́n fọ́ sí wẹ́wẹ́; mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá tí wọ́n rì; mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n fi iná jó; mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀, nítorí ti gbígbọ̀n-rìrì rẹ̀. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí mo rí àwọn nkan wọ̀nyí, mo rí ikũkù òkùnkùn ná à, tí ó kọjá kúrò ní ojú àgbáyé; sì kíyèsĩ, mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí kò tí ì ṣubú nítorí ìdájọ́ nlá àti tí ó lẹ́rù ti Olúwa. Mo sì rí àwọn ọ̀run tí wọn ṣí sílẹ̀, Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run ná à sì nsọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run; ó sì wá sísàlẹ̀ ó sì fi ara rẹ̀ hàn sí wọn. Mo sì tún rí mo sì jẹ́rĩ pé Ẹ̀mí Mímọ́ bà sórí àwọn méjìlá míràn; a sì ṣe Ìlànà wọn nípa Ọlọ́run, a sì yàn wọ́n. Angẹ́lì ná à sì bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Kíyèsí àwọn ọmọ-èhìn méjẽjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, tí a yàn láti ṣe ìránṣé fún irú-ọmọ rẹ. Ó sì wí fún mi: Ìwọ rántí àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́àgùtàn bí? Kíyèsĩ, àwọn ni wọn yíò ṣe ìdájọ́ àwọn ẹ̀yà méjẽjìlá ti Isráẹ́lì; nítorí-èyi, àwọn ìránṣẹ́ méjìlá ti irú-ọmọ rẹ ni a ó ṣeìdájọ́ fún nípa ọwọ́ wọn; nítorí ará ilé Isráẹ́lì ni ìwọ. Àwọn ìránṣẹ́ méjìlá tí ìwọ sì rí yí yíò ṣe ìdájọ́ irú-ọmọ rẹ. Sì kíyèsĩ, wọ́n jẹ́ olódodo títí láé; fún nítorí ti ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run àwọn ẹ̀wù wọn ni a sọ di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Wò ó! Mo sì wò, mo sì rí ìran mẹ́ta tí ó rékọjá nínú òdodo; àwọn ẹ̀wù wọn sì funfun tí ó tilẹ̀ dàbí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run. Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Àwọn wọ̀nyí ni a sọ di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn, nítorí ti ìgbàgbọ́ wọn nínú rẹ̀. Èmi, Nífáì, sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran kẹrin pẹ̀lú tí ó rékọjá nínú òdodo. Ó sì ṣe tí mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn ayé tí wọ́n jùmọ̀ péjọ. Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Kíyèsí irú-ọmọ rẹ, àti irú-ọmọ arákùnrin rẹ pẹ̀lú. Ó sì ṣe tí mo wò tí mo sì rí àwọn ènìyàn irú-ọmọmi tí wọ́n jùmọ̀ péjọ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ dojúkọ iru-ọmọ arákùnrin mi; wọ́n sì jùmọ̀ péjọ láti jagun. Angẹ́lì ná à sì bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Kíyèsí orísun omi eléerí èyí tí bàbá rẹ rí; bẹ̃ni, àní odò èyí tí ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀; ibú èyí ná à sì jẹ́ ibú ọ̀run àpãdì. Òwúsúwusù òkùnkùn nã sì jẹ́ ìdánwò ti èṣù, èyí tí ó fọ́ni lójú, tí ó sé àyà àwọn ọmọ ènìyàn le, tí ó sì tọ́ wọn kúrò sínú àwọn ọ̀nà gbọ́rò, tí wọ́n ṣègbé tí wọ́n sì sọnù. Ilé tí ó tóbi tí ó sì gbọ́rò nã, èyí tí bàbá rẹ rí, jẹ́ ìrò asán àti ìgbéraga àwọn ọmọ ènìyàn. Ọ̀gbun nlá tí ó sì banilẹ́rù kan sì pín wọn; bẹ̃ni, àní ọ̀rọ̀ àìṣègbè Ọlọ́run Ayérayé, àti ti Messia ẹni tí ó jẹ́ Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, nípa ẹni tí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ẹ̀rí, láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé títí di ìgbà yí, àti láti ìgbà yí lọ àti títí láé. Ní àkókò tí angẹ́lì nã sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, mo kíyèsí mo sì ríi wípé irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi dojú ìjà kọ irúọmọ tèmi, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ angẹ́lì ná à; àti nítorítí ìgbéraga irú-ọmọ mi, àti ìdánwò èṣù, mo kíyèsĩ i pé irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi borí àwọn ènìyàn irú-ọmọ mi. Ó sì ṣe tí mo kíyèsĩ, tí mo sì rí àwọn ènìyàn irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi tí wọ́n ti ṣẹ́gun irú-ọmọ mi; wọ́n sì ńkàkiri ní ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn lórí ojú ilẹ̀. Mo sì rí wọn tí wọ́n jùmọ̀ péjọ ní ọ̀gọ̣́gọ̀ ènìyàn; mo sì rí ogun àti ìró ogun lãrín wọn; nínú ogun àti ìró ogun ni mo sì rí ọ̀pọ̀ ìran tí wọ́n kọjá kúrò. Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Kíyèsĩ àwọn wọ̀nyí yíò rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́. Ó sì ṣe tí mo kíyèsĩ i, lẹ́hìn tí wọn ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ wọ́n di dúdú, àti ẹlẹ́gbin, àti elẽrí ènìyàn, tí ó kún fún ìmẹ́lẹ́ ati onirũru ohun ìríra. 13 Nífáì rí ìjọ onígbàgbọ́ ti èṣù tí a gbékalẹ̀ lãrín àwọn Kèfèrí nínú ìran, ó rí àwárí àti ìtẹ ilẹ dó Amẹ́ríkà, ìpàdánù ọ̀pọ̀lopọ̀ abala Bíbélì èyítí ó rí kerekere tí ó sì jẹ́ iyebíye, ipò ìparí ìṣubú-kúrò nínú òtítọ́ àwọn Kèfèrí, ìmúpadà sípò ìhìn-rere, bíbọ̀ jáde ìwé-mímọ́ti ọjọ́ ìkẹhìn, àti kíkọ́ sókè Síónì. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí angẹ́lì ná à bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Wò ó! Mo sì wò mo sì kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìjọba. Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Kíni ìwọ se àkíyèsí? Mo sì wípé: Mo kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìjọba. Ó sì wí fún mi: Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ-èdè àti àwọn ìjọba àwọn Kèfèrí. Ó sì ṣe tí mo rí ìdásílẹ̀ ìjọ onígbàgbọ́ nlá kan lãrín àwọn orílẹ̀-èdè àwọn Kèfèrí. Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Kíyèsí ìdásílẹ̀ ìjọ onígbàgbọ́ kan, èyí tí ó rínilára jùlọ tayọ gbogbo àwọn ìjọ onígbàgbọ́ míràn, èyi tí ó pa àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run, bẹ̃ni, tí ó sì fi iya jẹ wọn àti tí ó dè wọ́n mọ́lẹ̀, àti tí ó fi àjàgà kọ́rùn wọn pẹ̀lú àjàgà irin, àti tí ó rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ sínú ìgbèkun. Ó sì ṣe tí mo kíyèsí ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára yí; mo sì rí èṣù pé òun ni olùdásílẹ̀ rẹ̀. Bẹ̃gẹ́gẹ́ ni mo sì rí wúrà, àti fàdákà, àti àwọn aṣọ ṣẹ́dà, àti àwọn aláwọ̀ òdòdó, àti aṣọ ọ̀gbọ tí ìlọ́pọ̀ rẹ̀ dára, àti oríṣiríṣi aṣọ wíwọ̀ oníyebíye; mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn panṣágà obìnrin. Angẹ́lì ná à sì bá mi sọ̀rọ̀ wípé: Kíyèsí wúrà nã, àti fàdákà nã, àti àwọn aṣọ ṣẹ́dà nã, àti àwọn aláwọ òdòdó nã, àti aṣọ ọ̀gbọ tí ìlọ́pọ̀ rẹ̀ dára nã, àti asọ̀ wíwọ̀ oníyebíye nã, àti àwọn panṣágà obìnrin nã, wọ́n jẹ́ ìfẹ́ ijọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára yí. Àti pẹ̀lú nítorí ìyìn ayé ni wọ́n fi run àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ sínú ìgbèkun. Ó sì ṣe tí mo wò tí mo sì kíyèsí omi púpọ̀; wọ́n sì pín àwọn Kèfèrí kúrò ní irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi. Ó sì ṣe tí angẹ́lì ná à wí fún mi: Kíyèsĩ, ìbínú Ọlọ́run wà lórí irú-ọmọ àwọn arákùnrin rẹ. Mo sì wò mo sì kíyèsí ọkùnrin kan lãrín àwọn Kèfèrí nì, ẹni tí omi púpọ̀ nì yà-sọ̀tọ̀ kuro ní irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi; mo sì kíyèsí Ẹ̀mí Ọlọ́run, tí ó sọ̀kalẹ̀ tí ó sì siṣẹ́ lórí ọkùnrin nã; ó sì jáde lọ sórí omi púpọ̀, àní sí ọ̀dọ̀ irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi, tí wọ́n wà ní ilẹ̀ ìlérí. Ó sì ṣe tí mo kíyèsí Ẹ̀mí Ọlọ́run, tí ó siṣẹ́ lórí àwọn Kèfèrí míràn; wọ́n sì ti ìgbèkun jáde wá, sórí omi púpọ̀ nã. Ó sì ṣe tí mo kíyèsí ọjọ̣́rọ àwọn Kèfèrí lórí ilẹ̀ ìlérí; mo sì kíyèsí ìbínú Ọlọ́run, tí ó wà lórí irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi; a sì tú wọn ká níwájú àwọn Kèfèrí, a sì pa wọ́n run. Mo sì kíyèsí Ẹ̀mí Olúwa, tí o wà lórí àwọn Kèfèrí ná à, wọ́n sì ṣe rere, wọ́n sì gba ilẹ̀ ná à fún ìní wọn; mo sì kíyèsĩ pé wọ́n funfun, wọ́n sì dára, wọ́n sì lẹ́wà lọ́pọ̀lọpọ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn ènìyàn mi kí a tó pa wọ́n. Ó sí ṣe tí èmi, Nífáì, kíyèsĩ i, tí àwọn Kèfèrí tí ó ti jáde lọ kúrò nínú ìgbèkun rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Olúwa; agbára Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn. Mo sì kíyèsĩ i pé àwọn ìyá Kèfèrí wọn jùmọ̀ péjọ sóríomi, àti sórí ilẹ̀ pẹ̀lú, láti dojú ìjà kọ wọ́n. Mo sì kíyèsĩ i pé agbára Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn, àti pẹ̀lú pé ìbínú Ọlọ́run wà lórí gbogbo àwọn tí wọ́n jùmọ̀ péjọ láti dojú ìjà kọ wọ́n. Èmi, Nífáì, sì kíyèsĩ i pé àwọn Kèfèrí tí ó tí lọ kúrò nínú ìgbèkun ni a gbà nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè míràn. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, kíyèsĩ i pe wọ́n ṣe rere ní ilẹ̀ ná à; mo sì kíyèsí ìwé kan, a sì gbé e kiri lãrín wọn. Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Ìwọ́ mọ́ ìtumọ̀ ìwé ná à bí? Mo sì wí fún un: Èmi kò mọ̀. Ó sì wí pé: Kíyèsĩ i, ó jáde láti ẹnu Jũ kan. Èmi, Nífáì, sì kíyèsĩ; ó sì wí fún mi: Ìwé tí ìwọ kíyèsĩ jẹ́ ìwé-ìrántí àwọn Jũ, èyí tí ó ní májẹ̀mú Olúwa nínú, èyí tí ó ti ṣe sí ará ilé Isráẹ́lì; ó sì tún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìsọtẹ́lẹ́ àwọn wòlĩ mímọ́ nínú; ó sì jẹ́ ìwé-ìrántí tí ìfín tí ó wà lórí àwọn àwo idẹ, àfi pé kò pọ̀ tó bẹ̃; bíótilẹ̀ríbẹ̃, wọ́n ní awọn májẹ̀mú Olúwa nínú, èyí tí ó ti ṣe sí ará ilé Isráẹ́lì; nítorí-èyi, wọ́n jẹ́ iye nlá sí àwọn Kèfèrí. Angẹ́lì Olúwa ná à sì wí fún mi: Ìwọ ti kíyèsĩ i pé ìwé ná à jáde kúrò láti ẹnu Jũ kan; nígbàtí ó sì jáde kúrò láti ẹnu Jũ kan ó kún fún ẹ̀kún ìhìn-rere Olúwa, nípa ẹnití àwọn àpóstélì méjẽjìlá jẹ́rĩ; wọ́n sì jẹ́rĩ gẹ́gẹ́bí òtítọ́ èyítí mbẹ nínú Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run. Nítorí-èyi, àwọn ohun wọ̀nyí jáde lọ lọ́wọ́ àwọn Jũ ní mímọ́ sí àwọn Kèfèrí, gẹ́gẹ́bí òtítọ́ èyí tí ó mbẹ nínú Ọlọ́run. Lẹ́hìn tí wọ́n sì jáde lọ láti ọ́wọ́ àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, láti ọwọ́ àwọn Jũ sí àwọn Kèfèrí, ìwọ rí ìdásílẹ̀ ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára, èyí tí o rínilára ga ju gbogbo àwọn ìjọ onígbàgbọ́ míràn lọ; nítorí kíyèsĩ i, wọ́n ti mú kúrò nínú ìhìn-rere Ọ̀dọ́-àgùtàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ abala èyítí ó rí kerekere tí ó sì jẹ́ iyebíye jùlọ; àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ májẹ̀mú Olúwa ni wọ́n ti mú kúrò. Gbogbo èyí ni wọ́n sì ti ṣe kí wọn kí ó lè yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po, kí wọn kí ó lè fọ́ ojú, kí wọ́n sì sé àyà àwọn ọmọ ènìyàn le. Nítorí-èyi, ìwọ rí wípé lẹ́hìn tí ìwé ná à ti jáde lọ nípa ọwọ́ ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára ná à, pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun tí wọ́n rí kerekere tí wọ́n sì jẹ́ iyebíye ni ó wà tí a mú kúrò nínú ìwé ná à, èyí tí ó jẹ́ ìwé Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run. Lẹ́hìn tí a sì ti mú àwọn ohun kerekere tí ó sì jẹ́ iyebíye wọ̀nyí kúrò, ó jáde lọ sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àwọn Kèfèrí; lẹ́hìn tí ó sì jáde lọ sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àwọn Kèfèrí tán, bẹ̃ni, àní rékọjá omi púpọ̀ èyí tí ìwọ ti rí pẹ̀lú àwọn Kèfèrí èyí tí ó ti jáde lọ kúrò ní ìgbèkun, ìwọ rí i—nítorítí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun kerekere tí ó sì jẹ́ iyebíye èyí tí a ti mú kúrò nínú ìwé ná à, èyí tí ó wà kerekere sí ìmọ̀ àwọn ọmọ ènìyàn, gẹ́gẹ́bí ti kerekere èyí tí ó wà nínú Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run—nítorí ti àwọn ohun wọ̀nyí tí a mú jáde kúrò nínú ìhìn-rere Ọ̀dọ́-àgùtàn, ọ̀pọ̀ nlá lọ́pọ̀lọpọ̀ ni ó kọsẹ̀, bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí Sátánì ní agbára nlá lórí wọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ìwọ kíyèsí pé àwọn Kèfèrí tí o ti jáde lọ kuro nínú ìgbèkun, tí a sì ti gbé sókè nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run ga ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè míràn lọ, lórí ojú ilẹ̀ èyí tí ó jẹ́ àsàyàn ga ju gbogbo àwọn ilẹ̀ míràn lọ, èyí tí ó jẹ́ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run ti fi dá májẹ̀mú pẹ̀lú bàbá rẹ pé irú-ọmọ rẹ̀ yíò ní i fún ilẹ̀ ogún wọn; nítorí-èyi, ìwọ rí i pé Olúwa Ọlọ́run kì yíò jẹ ki àwọn Kèfèrí pa àdàpọ̀ irú-ọmọ rẹ run pátápátá, èyí tí o wà lãrín àwọn arákùnrin rẹ. Bẹ̃ni òun kì yíò jẹ́ kí àwọn Kèfèrí pa irú-ọmọ àwọn arákùnrin rẹ run. Bẹ̃ni Olúwa Ọlọ́run kì yíò jẹ́ kí àwọn Kèfèrí dúró títí láé nínú ipò ìfọ́jú búburú nã, èyí tí ìwọ kíyèsĩ pé wọ́n wà nínú rẹ̀, nítorítí àwọn abala ìhìn-rere Ọ̀dọ́-àgùtàn tí ó rí kerekere tí ó sì jẹ́ iyebíye jùlọ èyí ti ìjọ onígbàgbọ́ tí ó rínilára ná à ti pamọ́ sẹ́hìn, ìdásílẹ̀ èyí tí ìwọ ti rí. Nítorí-èyi ni Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run sọ wípé: Èmi yíò ni ãnú sí àwọn Kèfèrí, sí bíbẹ̀wò ìyókù ará ilé Isráẹ́lì ní ìdájọ́ nlá. Ó sì ṣe tí angẹ́lì Olúwa ná à bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Kíyèsĩ, ni Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run ná à wí, lẹ́hìn tí mo bá ti bẹ ìyókù ará ilé Isráẹ́lì wò—ìyókù yí nípa ẹni tí èmi sọ̀rọ̀ sì jẹ́ irú-ọmọ bàbá rẹ—nítorí-èyi, lẹ́hìn tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò ní ìdájọ́, tí a sì kọlũ wọ́n nípa ọwọ́ àwọn Kèfèrí, lẹ́hìn tí àwọn Kèfèrí ná à sì kọsẹ̀ làpọ̀jù, nítorí ti àwọn abala ìhìn-rere Ọ̀dọ́-àgùtàn tí o rí kerekere tí ó sì jẹ́ iyebíye jùlọ èyí tí a ti pamọ́ sẹ́hìn nípa ọwọ́ ìjọ onígbàgbọ́ tí o rínilára ná à, èyí tí ó jẹ́ ìyá àwọn panṣágà obìnrin, ni Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à wí—Èmi yíò ni ãnú sí àwọn Kèfèrí ní ọjọ́ ná à, tóbẹ̃ tí èmi yíò mú jáde sí wọn, ní agbára ọwọ́ ara tèmi, púpọ̀ nínú ìhìn-rere mi, èyí tí yíò jẹ́ kerekere àti iyebíye, ni Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à wí. Nítorí, kíyèsĩ, ni Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à wí: Èmi yíò fi ara mi hàn sí irú-ọmọ rẹ, tí wọn yíò kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun èyí tí èmi yíò jíṣẹ́ sí wọn, èyí tí yíò jẹ́ kerekere àti iyebíye; lẹ́hìn tí a bá sì pa irú-ọmọ rẹ run, tí wọ́n sì rẹ́hìn nínú ìgbàgbọ́, àti irú-ọmọ àwọn arákùnrin rẹ pẹ̀lú, kíyèsĩ, àwọn ohun wọ̀nyí ni wọn yíò pamọ́, láti jáde wá sí àwọn Kèfèrí, nípasẹ̀ ẹ̀bùn àti agbára Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à. Nínú wọn ni a ó sì kọ ìhìn-rere mi sí, ni Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à wí, àpáta mi àti ìgbàlà mi. Alábùkún-fún ni àwọn ẹni tí yíò wá láti mu Síónì mi jáde wá ní ọjọ́ ná à, nítorí wọn ó ní ẹ̀bùn àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́; bí wọ́n bá sì rọ́jú dé òpin a ó gbé wọn sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn, a ó sì gbà wọ́n là ní ìjọba àìlópin Ọ̀dọ-àgùtàn; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì kéde àlãfíà, bẹ̃ni, ìhìn ayọ̀ nlá, báwo ni wọn yíò lẹ́wà tó lórí àwọn òkè gíga. Ó sì ṣe tí mo kíyèsí ìyókù irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi, àti pẹ̀lú ìwé Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, èyí tí ó ti jáde lọ síwájú láti ẹnu àwọn Jũ, pé ó jáde wá lọ́wọ́ àwọn Kèfèrí sí ìyókù irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi. Lẹ́hìn tí ó sì ti jáde wá sí wọn mo kíyèsí àwọn ìwé míràn,èyí tí o jáde wá nípasẹ̀ agbara Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à, láti ọwọ́ àwọn Kèfèrí sí wọn, sí yíyí lọ́kàn padà àwọn Kèfèrí àti ìyóku iru-ọmọ àwọn arákùnrin mi, àti pẹ̀lú àwọn Jũ ti a túká sórí gbogbo ori ilẹ àgbáyé, pe àwọn ìwé ìrántí ti àwọn wòlĩ àti ti àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn jẹ́ òtítọ́. Angẹ́lì ná à sì wí fún mi, wípé: Àwọn ìwé ìrántí ìkẹhìn wọ̀nyí, èyí tí ìwọ ti rí lãrín àwọn Kèfèrí, yíò fi ìdí òtítọ́ ti èkíní mulẹ̀, èyí ti o jẹ́ ti àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, yíò sì sọ àwọn ohun kerekere àti iyebíye náà di mímọ̀ èyí tí a ti gbà kúrò lọ́wọ́ wọn; tí a ó sì sọ di mímọ̀ sí gbogbo àwọn ìbátan, èdè, àti ènìyàn, pé Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run ná à jẹ́ Ọmọ Bàbá Ayérayé, àti Olùgbàlà ayé; àti pé gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, bíbẹ̃kọ́ a kò lè gbà wọ́n là. Wọ́n sì gbọ́dọ̀ wá gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí a ó fi múlẹ̀ lati ẹnu Ọ̀dọ́-àgùtàn; àwọn ọ̀rọ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à ni a ó sì sọ di mímọ̀ nínú àwọn ìwé ìrántí irúọmọ rẹ, àti gẹ́gẹ́ bẹ̃ ná à nínú àwọn ìwé ìrántí àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à; nítorí-èyi àwọn méjẽjì ni a ó fi múlẹ̀ nínú ẹyọ̀kan; nítorí Ọlọ́run kan àti Olùṣọ́-àgùtàn kan ni ó wà lórí gbogbo ayé. Ìgbà ná à sì mbọ̀ tí òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti sí àwọn Jũ àti pẹ̀lú sí àwọn Kèfèrí; lẹ́hìn tí ó bá sì ti fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn Jũ àti pẹ̀lú sí àwọn Kèfèrí, nígbànã ni òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn Kèfèrí àti pẹ̀lú sí àwọn Jũ, àwọn ẹni ìkẹ́hìn yíò sì di ti àkọ́kọ́, ti àkọ́kọ́ yíò sì di ti ìkẹhìn. 14 Angẹ́lì kan sọ fún Nífáì nípa awọn ìbùkún àti awọn ègún tí yíò wá sí órí àwọn Kèfèrí—Àwọn ìjọ onígbàgbọ́ méjì péré ni ó wà: ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run àti ìjọ onígbàgbọ́ ti èṣù—Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti Ọlọ́run ní gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì ṣe inúnibíni sí—Àpóstélì Jòhánnù yíò kọ̀wé nípa òpin ayé. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa. Yíò sì ṣe, tí bí àwọn Kèfèrí bá fetí sí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run ní ọjọ́ ná à tí òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí wọn ní ninu ọ̀rọ̀, àti pẹ̀lú ninu agbára, ní ìṣe gbogbo, sí mímú kúrò àwọn ohun ìkọsẹ̀ wọn— Tí wọn kò sì sé àyà wọn le sí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, a ó sì kà wọ́n mọ́ irú-ọmọ bàbá rẹ; bẹ̃ni, wọn a ó sì kà wọ́n mọ́ ìdílé Isráẹ́lì; wọn yíò sì jẹ́ ẹni ìbùkún ní orí ilẹ̀ ìlérí titi; lae a kò ní rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ mọ́ sínú ìgbèkun; àti pé a kò ní fọn ìdílé Isráẹ́lì ká mọ́. Àti ọ̀gbun nlá nì, èyí tí a t i gbẹ́ fún wọn nípasẹ̀ ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì, èyí tí a dásílẹ̀ nípa ọwọ́ èṣù àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí òun kí ó lè tọ́ ọkàn àwọn ènìyàn kúrò sísàlẹ̀ ọ̀run àpãdì—bẹ̃ni, ọ̀gbun nlá nì èyí tí a ti gbẹ́ fún ìparun àwọn ènìyàn ni a ó kún pẹ̀lú àwọn ẹni tí ó gbẹ́ ẹ, sí ìparun wọn pátápátá, ni Ọ̀dọ-àgùtàn Ọlọ́run wí; kì í ṣe ìparun tiọkàn, bíkòṣe ti jíjù rẹ̀ sínú ọ̀run àpãdì nì, èyí tí kò ní òpin. Nítorí kíyèsĩ, èyí jẹ́ gẹ́gẹ́bí ìgbèkun ti èṣù, àti pẹ̀lú gẹ́gẹ́bí àìṣègbè Ọlọ́run, lórí gbogbo àwọn ẹni tí yíò ṣe iṣẹ́ ìwà búburú àti ẹ̀gbin níwájú rẹ̀. Ó sì ṣe tí angẹ́lì ná à wí fún èmi, Nífáì, wípé: Ìwọ ti kíyèsĩ pé tí àwọn Kèfèrí bá ronúpìwàdà yíò dara fún wọn; ìwọ sì mọ̀ pẹ̀lú nípa awọn májẹ̀mú Olúwa sí ará ilé Isráẹ́lì; ìwọ sì ti gbọ́ pẹ̀lú pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ronúpìwàdà kò lè ṣàì ṣègbé. Nítorínã, ègbé ni fún àwọn Kèfèrí bí ó bá rí bẹ́ ẹ̀ pé wọ́n sé ọkàn wọn le sí Ọ̀dọ-àgùtàn Ọlọ́run. Nítorí ìgbà ná à mbọ̀ wa, ni Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run wí, tí èmi yíò ṣiṣẹ́ nlá àti iṣẹ́ ìyanu lãrín àwọn ọmọ ènìyàn; iṣẹ́ èyí tí yíò jẹ́ títí ayé, yálà ni ọ̀nà kan tàbí ní ti òmíràn—yálà sí yíyí wọn lọ́kàn padà sí àlãfíà àti ìyè ayeraye, tàbí sí jíjọ̀lọ́wọ́ wọn sí líle ọkàn wọn àti fífọ́lójú ọkàn wọn sí mímú wọn wá sílẹ̀ sínú ìgbèkùn, àti pẹ̀lú sínú ìparun, ní ti ayé yí àti ní ti ẹ̀mí pẹ̀lú, ní ìbámu pẹ̀lú ìgbèkùn èṣù, nípa èyí tí mo ti sọ̀. Ó sì ṣe nígbàtí angẹ́lì ná à ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó wí fún mi: Ìwọ rántí awọn májẹ̀mú Baba sí ará ilé Isráẹ́lì bí? Mo wí fún un: Bẹ̃ni. Ó sì ṣe tí ó wí fún mi: Wò ó, sì kíyèsí ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì, èyí tí i ṣe ìyá àwọn ìríra, tí olùdásílẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ èṣù. Ó sì wí fún mi: Kíyèsĩ ìjọ onígbàgbọ́ méjì péré ni ó wà; ọ̀kan jẹ́ ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, ìkejì sì jẹ́ ìjọ onígbàgbọ́ ti èṣù; nítorí-èyi, ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe ti ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run nṣe ti ijọ onígbàgbọ́ nlá nì, èyí tí ó jẹ́ ìyá àwọn ìríra; òun sì ni àgbèrè gbogbo ayé. Ó sì ṣe tí mo wò tí mo sì kíyèsí àgbèrè gbogbo ayé, ó sì jókò lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi; ó sì ní ìjọba lórí gbogbo ayé, lãrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn gbogbo. Ó s ì ṣe t í mo kíyèsí ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, iye rẹ̀ sì jẹ́ díẹ́, nítorí ti ìwà búburú àti awọn ohun ìríra àgbèrè tí ó jókò lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi; bíótilẹ̀ríbẹ̃ mo kíyèsĩ pé ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, tí wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run, wà pẹ̀lú lórí gbogbo ojú àgbàyé; àwọn ìjọba wọn lórí gbogbo ojú àgbáyé sì jẹ́ kékeré, nítorí ti ìwa búburú àgbèrè nlá nì ẹni tí èmi rí. Ó sì ṣe tí mo kíyèsĩ i tí ìyá nlá awọn ìríra nì jùmọ̀ kó ọ̀pọ̀ ènìyàn jọ sórí ojú gbogbo àgbáyé, lãrín gbogbo àwọn orílè-èdè àwọn Kèfèrí, láti dojú ìjà kọ Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, kíyèsí agbára Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, tí ó sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn mímọ́ ti ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, àti sórí àwọn ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa, àwọn tí a túká sórí gbogbo ojú àgbáyé; wọ́n sì gbáradì pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá. Ó sì ṣe tí mo kíyèsĩ pé a tú ìbínú Ọlọ́run jáde sórí ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì, tóbẹ̃ tí ogun àti ìró ogun wàlãrín gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ìbátan ayé. Bí ogun àti ìró ogun sì ti bẹ̀rẹ̀ lãrín gbogbo àwọn orílẹ̀èdè tí nṣe ti ìyá awọn ohun ìríra nì, angẹ́lì ná à wí fún mi, wípé: Kíyèsĩ i, ìbínú Ọlọ́run nbẹ lórí ìyá àwọn panṣágà obìnrin; sì kíyèsĩ i, ìwọ rí gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí— Nígbàtí ọjọ́ ná à bá sì dé tí a ó tú ìbínú Ọlọ́run jáde sórí ìyá àwọn panṣágà obinrin nì, èyí tí ó jẹ́ ìjọ onígbàgbọ nlá tí o sì rínilára ti gbogbo ayé, tí ẹni tí ó ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ èṣú, nígbànã, ní ọjọ́ ná à, iṣẹ́ Bàbá yíò bẹ̀rẹ̀, ní pípa ọ̀nà mọ́ fún mímú awọn májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ, èyí tí ó ti ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ará ilé Isráẹ́lì. Ó sì ṣe tí angẹ́lì ná à wí fún mi, wípé: Wò ó! Mo sì wò mo sì kíyèsí ọkùnrin kan, ó sì wọ asọ̀ funfun. Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Ṣá wo ọ̀kan nínú àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn. Kíyèsĩ i, òun yíò rí yíò sì kọ ìyókù àwọn ohun wọ̀nyí; bẹ̃ni, àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èyí tí ó ti wà. Òun yíò sì kọ̀wé pẹ̀lú nípa òpin ayé. Nítorí-èyi, àwọn ohun èyí tí òun yíò kọ jẹ́ àìṣègbè àti òtítọ́; sì kíyèsĩ i a kọ wọ́n sínú ìwé èyí tí ìwọ kíyèsí tí ó njáde wá láti ẹnu àwọn Jũ; ní ìgbà tí wọ́n sì jáde wá láti ẹnu àwọn Jũ, tàbí, ní ìgbà tí ìwé ná à jáde wá láti ẹnu àwọn Jũ, àwọn ohun èyí tí a kọ tẹ́jú, wọ́n sì dá ṣáká, wọ́n sì jẹ́ iyebíye jùlọ, wọ́n sì ní-rọ̀rùn sí ìmọ̀ gbogbo ènìyàn. Sì kíyèsĩ i, àwọn ohun èyí tí àpóstélì Ọ̀dọ́-àgùtàn yí yíò kọ jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èyí tí ìwọ ti rí; sì kíyèsĩ i, ìyókù ni ìwọ yíò rí. Ṣùgbọ́n àwọn ohun èyí tí ìwọ yíò rí lẹ́hìn èyí ìwọ kì yíò kọ; nítorí Olúwa Ọlọ́run ti yan àpóstélì Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run nì pé òun yíò kọ wọ́n. Àti pẹ̀lú àwọn míràn tí ó ti wà, ó ti fi ohun gbogbo hàn sí wọn, a sì fi èdìdì dì wọ́n láti jáde wá ní mímọ wọn, gẹ́gẹ́bí òtítọ́ èyí tí mbẹ nínú Ọ̀dọ́-àgùtàn, ní àkókò tí o yẹ níti Olúwa, sí ará ilé Isráẹ́lì. Èmi, Nífáì, sì gbọ́ mo sì jẹ́rĩ, pé orúkọ àpóstélì Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à ni Jòhánnù, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ angẹ́lì ná à. Sì kíyèsĩ i, Èmi, Nífáì, ni a dá lẹ́kun láti kọ ìyókù àwọn ohun èyí tí mo rí tí mo sì gbọ́; nítorí-èyi àwọn ohun èyí tí mo ti kọ tẹ̀mi lọ́rùn; èyí tí mo kọ sìjẹ́ apákan díẹ̀ ti àwọn ohun èyí tí mo rí. Mo sì jẹ́rĩ pé mo rí àwọn ohun èyí tí bàbá mi rí, angẹ́lì Olúwa ná à sì ṣe wọ́n ní mímọ̀ sí mi. Àti nísisìyí mo ṣe òpin ti ìsọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun èyí tí mo rí nígbàtí a mú mi lọ nínú ẹ̀mí, bí nkò tilẹ̀ sì kọ gbogbo àwọn ohun èyí tí mo rí, àwọn ohun èyí tí mo ti kọ jẹ́ òtítọ́. Báyĩ ni ó sì rí. Àmín. 15 Irú-ọmọ Léhì yíò gba ìhìn-rere lọ́wọ́ àwọn Kèfèrí ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn—Kíkojọ Isráẹ́lì ni a fi wé igi ólífí èyí tí a ó tún lọ́ àwọn ẹká àdánidá rẹ̀ sínú rẹ̀—Nífáì túmọ̀ ìran igi ìyè ó sọ̀rọ̀ nípa àìṣègbè Ọlọ́run ní yíya ènìyan búburú nípa kuro ní olódodo. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí a ti mú èmi, Nífáì, lọ nínú ẹ̀mí, tí mo sì ti rí gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí, mo padà sí àgọ́ bàbá mi. Ó sì ṣe tí mo kíyèsí àwọn arákùnrin mi, wọ́n sì ṣe àríyànjiyàn pẹ̀lú ara wọn nípa àwọn ohun èyí tí bàbá mi ti sọ fún wọn. Nítorí ó sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nlá fún wọn nítọ́tọ́, èyí tí o ṣòro láti mọ̀, àfi tí ènìyàn bá bèrè lọ́wọ́ Olúwa; níwọ̀n bí wọ́n sì ti le ní ọkàn wọn, nítorínã àwọn kò yí ojú sí Olúwa bí àwọn ìbá ṣe ṣe. Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kẹ́dùn nítorí ti líle ọkàn wọn, àti pẹ̀lú, nítorí ti àwọn ohun èyí tí mo ti rí, mo sì mọ̀ pé láìyẹ̀kúrò wọn kò le ṣe àìṣẹlẹ̀ nítorí ti ìwà búburú àwọn ọmọ ènìyàn. Ó sì ṣe tí a borí mi nítorí ti àwọn ìpọ́njú mi, nítorí mo gbèrò pé àwọn ìpọ́njú mi pọ̀ ju gbogbo ìpọ̀njú lọ, nítorí ti ìparun àwọn ènìyàn mi, nítorí mo t i rí ìṣubú wọn. Ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí mo ti gba agbara mo bá àwọn arákùnrin mi sọ̀rọ̀, mo nfẹ́ láti mọ̀ lọ́wọ́ wọn ìdí àwọn àríyànjiyàn wọn. Wọ́n sì ní: Kíyèsĩ i, àwa kò lè mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí bàbá wa ti sọ nípa àwọn ẹ̀ká àdánidá igi ólífì, àti pẹ̀lú nípa àwọn Kèfèrí. Mo sì wí fún wọn: Njẹ́ ẹ̀yin ti bèrè lọ́wọ́ Olúwa? Wọ́n sì wí fún mi: Àwa kò tí ì ṣe bẹ́ ẹ̀; nítorí Olúwa kò fi irú ohun bẹ́ ẹ̀ hàn sí wa. Kíyèsĩ i, mo wí fún wọn: Báwo wá ni tí ẹ̀yin kò pa awọn òfin Olúwa mọ́? Báwo wá ni tí ẹ̀yin yíò ṣègbé, nítorí ti líle ọkàn yín? Ṣé ẹ̀yin kò rántí àwọn ohun èyí tí Olúwa ti sọ?—Bí ẹ̀yin kò bá mú ọkàn yín le, tí ẹ̀yin sì bí mí lẽrè ní ìgbàgbọ́, tí ẹ gbàgbọ́ pé ẹ̀yin yíò rí gbà, pẹ̀lú ãpọn ní pípa awọn òfin mi mọ́, dájúdájú àwọn ohun wọ̀nyí ni a ó fihàn sí i yín. Kíyèsĩ i, mo wí fún un yín, pe ará ilé Isráẹ́lì ni a fi wé igi ólífi, nípasẹ̀ Èmí Olúwa èyí tí ó wà nínú bàbá wa; sì kíyèsĩ i, njẹ́ àwa kò ti yapa kúrò nínú ará ilé Isráẹ́lì, njẹ àwa kì í sì í ṣe ẹ̀ká ará ilé Isráẹ́lì? Àti nísisìyí, ohun tí bàbá wa pète nípa lílọ́ sínú àwọn ẹ̀ká àdánidá nípa ẹ̀kún àwọn Kèfèrí, ni, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, nígbàtí irú-ọmọ wa yíò ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́, bẹ̃ni fun ìwọ̀n ọpọlọpọ ọdun, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ irandiran lẹhin tí a ó fi Messia hàn ní ara sí àwọn ọmọ ènìyàn, nígbànã ni ẹ̀kún ìhìn-rere ti Messia yíò wá sí ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí sí ọ̀dọ̀ ìyókù irú-ọmọ wa— Ní ọjọ́ nì sì ni ìyókù irú-ọmọ wa yíò mọ̀ pé àwọn jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì, àti pé àwọn ni ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa; nígbànã sì ni wọn yíò mọ̀ tí wọn ó sì wá sí ìmọ̀ àwọn baba-nlá wọn, àti pẹ̀lú sí ìmọ̀ ìhìn-rere ti Olùràpadà wọn, èyí tí a fi ṣe ìránṣẹ́ sí àwọn bàbá wọn nípasẹ̀ rẹ̀; nítorínã, wọn yíòwá sí ìmọ̀ Olùràpadà wọn àti àwọn nkan àfiyèsí ti ẹ̀kọ́ rẹ̀ gan, kí wọn lè mọ̀ bí wọ́n ó ṣe wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí a sì gbà wọ́n là. Nígbànã ní ọjọ́ nì, njẹ́ wọn kì yíò ha yọ̀ tí wọn yíò sì fi ìyìn fún Ọlọ́run Àìlópin wọn, àpáta wọn àti ìgbàlà wọn? Bẹ̃ni, ní ọjọ́ nì, njẹ́ wọn kì yíò ha gba agbára àti bíbọ́ lọ́wọ́ àjàrà òtítọ́? Bẹ̃ni, njẹ́ wọn kì yíò wá sí agbo òtítọ́ Ọlọ́run? Kíyèsĩ i, mo wí fún un yín, Bẹ̃ni; a ó tún rántí wọn lãrín ará ilé Isráẹ́lì; a ó lọ́ wọn, níwọ̀n bí wọ́n ṣe jẹ́ ẹ̀ká àdánidá igi ólífì, sínú igi ólífì tọ́tọ́. Èyí sì ni ohun tí bàbá wa pète; ó sì pète pé kì yíò ṣẹ títí di lẹ́hìn tí àwọn Kèfèrí yíò tu wọn ká; ó sì pète pé yíò wá nípasẹ̀ àwọn Kèferí, pé kí Olúwa lè fi agbára rẹ̀ hàn sí àwọn Kèfèrí, fún ìdí gan pé a ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ nípa àwọn Jũ, tàbí nípa ará ilé Isráẹ́lì. Nítorí-èyi, bàbá wa kò sọ̀rọ̀ nípa irú ọmọ wa nìkan, ṣùgbọ́n nípa gbogbo ará ilé Isráẹ́lì, ó ntọ́ka sí májẹ̀mú èyí tí a ó mú ṣẹ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn; májẹ̀mú èyí tí Olúwa ṣe pẹ̀lú bàbá wa Ábráhámù, tí ó wípé: Nínú irúọmọ rẹ ni a ó ti fi ìbùkún fún gbogbo ìbátan aráyé. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, sọ̀rọ̀ púpọ̀ fún wọn nípa àwọn nkan wọ̀nyí; bẹ̃ni, mo sọ̀rọ̀ fún wọn nípa ìmúpadà sípò àwọn Jũ ní àwọn ọjọ ìkẹhìn. Mo sì tún àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah kà sí wọn, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìmúpadà sípò àwọn Jũ, tàbí ará ilé Isráẹ́lì; lẹ́hìn tí a sì mú wọn padà sípò a kò ní fọn wọn ká mọ́, bẹ̃ni a kò ní tún tú wọn ká. Ó sì ṣe tí mo sọ àwọn ọ̀rọ̀ púpọ̀ sí àwọn arákùnrin mi, tí wọ́n gbẹ̀rọ̀ tí wọ́n sì rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Olúwa. Ó sì ṣe tí wọ́n tún bá mi sọ̀rọ̀, wọ́n nwí pé: Kíni ìtumọ̀ nkan yí èyí tí bàbá wa rí ní àlá? Kíni ìtumọ̀ igi èyí tí ó rí? Mo sì wí fún wọn: ó jẹ́ àwòrán igi ìyè. Wọn sì wí fún mi: Kíni ìtumọ̀ ọ̀pá irin èyí tí bàbá wa rí, tí ó tọ́ sí igi ná à? Mo sì wí fún wọn pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dì í mú kì yíò ṣègbé láé; bẹ̃ni ìdánwò àti àwọn ọfà iná èṣù kò lè borí wọn sí ìfọ́jù, láti tọ́ wọn kúrò sí ìparun. Nítorí-èyi, èmi, Nífáì, gbà wọ́n níyànjú láti ní akíyèsí sí ọ̀rọ̀ Olúwa; bẹ̃ni, mo gbà wọ́n níyànjú pẹ̀lú gbogbo okun-inú ọkàn mi, àti pẹ̀lú gbogbo iyè èyí tí mo ní ní ìní, pé kí wọ́n lè ní akíyèsí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì rántí láti pa awọn òfin rẹ̀ mọ́ nígbà-gbogbo ní ohun gbogbo. Wọ́n sì wí fún mi: Kíni ìtumọ̀ odò omi èyí tí bàbá wa rí? Mo sì wí fún wọn pé omi èyí tí bàbá mi rí nì jẹ́ ìwà ọ̀bùn; ọkàn rẹ̀ ni a sì ti gbémì púpọ̀ sínú àwọn ohun míràn tí kò kíyèsĩ ìwà ọ̀bùn omi ná à. Mo sì wí fún wọn pé ó jẹ́ ọ̀gbun tí ó dẹ́rùbani, èyí tí ó ya àwọn ènìyàn búburú sọ́tọ̀ kúrò lára igi ìyè, àti pẹ̀lú kúrò nínú àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run. Mo sì wí fún wọn pé ó jẹ́ àwòrán ọ̀run àpãdì búburú nì,èyí tí ángẹ́lì ná à wí fún mi pé a pèsè fún àwọn ènìyàn búburú. Mo sì wí fún wọn pé bàbá wa rí pẹ̀lú pé àìṣègbè Ọlọ́run bẹ̃gẹ́gẹ́ pín àwọn ènìyàn búburú kúrò lára olódodo; dídán èyí tí ó dàbí dídán ọ̀wọ̀ iná, èyí tí ó jó lọ sókè sí Ọlọ́run láé àti láéláé, tí kò sì ní òpin. Wọ́n sì wi fun mi: Ṣé ohun yí túmọ̀ sí ìdálóró ara ní àwọn ọjọ́ ìdánwò, tàbí ó túmọ̀ sí ipò ti ìgbẹ̀hìn ọkàn lẹ́hìn ikú ara ti ayé yí, tàbí ṣé ó sọrọ nípa àwọn ohun èyí tí ó jẹ́ ti ayé yí? Ó sì ṣe tí mo wí fún wọn pé ó jẹ́ àwòrán àwọn ohun ti ayé yí àti ti ẹ̀mí pẹ̀lú; nítorí ọjọ́ ná à yíò dé tí a kò lè ṣe àìṣe ìdájọ́ wọn ní ti iṣẹ́ wọn, bẹ̃ni, àní iṣẹ́ èyí tí wọ́n ṣe pẹ̀lú ara ti ayé yì ní àwọn ọjọ́ ìdánwò wọn. Nítorí-èyi, bí wọ́n bá kú nínú ìwà búburú wọn a gbọ́dọ̀ sọ wọ́n kúrò pẹ̀lú, nípa ti àwọn ohun èyí tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí, èyí tí ó nṣe ti òdodo; nítorí-èyi, a gbọ́dọ̀ mú wọn láti dúró níwájú Ọlọ́run, láti ṣe ìdájọ́ wọn ní ti iṣẹ́ wọn; bí iṣẹ́ wọn bá sì ti jẹ́ ìwà ẹ̀gbin o di dandan kí wọn ó ní ẹ́gbin; bí wọ́n bá sì ní ẹ́gbin, o di dandan ki wọn ò má lè gbé inu ìjọba Ọlọ́run; bí ó bá si ri bẹ, o di dandan ki ìjọba Ọlọ́run lẹ́gbin pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, mo wí fún yín, ìjọba Ọlọ́run kò ni ẹ́gbin, kò sì lè sí ohun àìmọ́ èyíkèyí tí yíò wọlé sínú ìjọba Ọlọ́run; nítorínã ó di dandan ki a pèsè ibi ẹlẹgbin kan fún ohun nã tí ó lẹ́gbin. Ibì kan sì wà tí a ti pèsè, bẹ̃ni, àní ọ̀run àpãdì búburú nì nípa èyí tí mo ti sọ̀rọ̀, èṣù sì jẹ́ olùpèsè rẹ̀; nítorí-èyi ipò ti ìgbẹ̀hìn ọkàn àwọn ènìyàn ni láti gbé ní ìjọba Ọlọ́run, tàbí kí á sọ wọ́n sóde nítorí ti àìṣègbè nípa èyí tí mo ti sọ̀rọ̀. Nítorí-èyi, àwọn ènìyàn búburú ni a kọ̀ sílẹ̀ kúrò ní ọ̀dọ̀ olódodo, àti pẹ̀lú kúrò ní ara igi ìyè nì, èso èyí tí o jẹ́ iyebíye jùlọ tí ó sì yẹ ní fífẹ́ tayọ gbogbo àwọn èso míràn lọ; bẹ̃ni, ó sì jẹ́ èyí tí ó tóbi jùlọ ní gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run. Báyĩ í ni mo sì wí fún àwọn arákùnrin mi. Àmín. 16 Àwọn ènìyàn búburú ka òtítọ́ sí líle—Àwọn ọmọkùnrin Léhì gbé àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì ní ìyàwó—Liahónà tọ́ wọn sí ọ̀ná nínú aginjù—Wọ́n nkọ àwọn ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa sórí Liahónà láti ìgbà dé ìgbà—Íṣmáẹ́lì kú; ìdílé rẹ̀ nkùn nítorí ìpọ́njú. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí èmi, Nífáì, tí fi òpin sí sísọ̀rọ̀ fún àwọn arákùnrin mi, kíyèsĩ wọ́n wí fún mi: Ìwọ ti kéde sí wa àwọn ohun líle, ju èyí tí àwa lè faradà. Ó sì ṣe tí mo wí fún wọn pé mo mọ̀ pé mo ti sọ àwọn ohun líle lòdì sí àwọn ènìyàn búburú, gẹ́gẹ́bí sí òtítọ́; àwọn olódodo sì ni mo ti dá láre, tí mo sì ti ṣe ìjẹ́rì í pé a ó gbé wọn sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn; nítorí èyí, ẹlẹ́ṣẹ̀ ka òtítọ́ sí líle, nítorí ó gún wọn ní ara. Àti nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi, bí ẹ̀yin bá ní ódodo tí ẹ sì nfẹ́ láti fetísílẹ̀ sí òtítọ́, tí ẹ sì ní ìkíyèsí sí i, pé kí ẹ̀yin lè rìn dẽdéníwájú Ọlọ́run, njẹ́ ẹ̀yin kò ní kùn nítorí òtítọ́, kí ẹ wípé: Ìwọ sọ àwọn ohun líle lòdì sí wa. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, gba àwọn arákùnrin mi níyànjú, pẹ̀lú gbogbo ãpọn, láti pa òfin Olúwa mọ́. Ó sì ṣe tí wọn rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Olúwa; tóbẹ̃ tí mo ní ayọ̀ àti ìrètí nlá sí wọn, pé kí wọ́n lè rìn ní ọ̀nà òdodo. Nísisìyí, gbogbo nkan wọ̀nyí ni a sọ tí a sì ṣe bí bàba mi ṣe ngbé nínú àgọ́ ní àfonífojì èyí tí ó pè ní Lẹ́múẹ́lì. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, gbé ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì ní aya; àti pẹ̀lú, àwọn arákùnrin mi gbé nínú àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì ní aya; àti pẹ̀lú Sórámù gbé àkọ́bí ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì ní aya. Báyĩ í sì ni bàbá mi ti mú gbogbo òfin Olúwa ṣẹ èyí tí a ti fi fún un. Àti pẹ̀lú, èmi, Nífáì, ni Olúwa ti bùkún fún lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó sì ṣe tí ohùn Olúwa wí fún bàbá mi ní òru, ó sì pàṣẹ fún un pé ní ọ̀la kí ó mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n sínú aginjù. Ó sì ṣe bí bàbá mi ti dìde ní òwúrọ̀, tí ó sì lọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, sí ìyalẹnù rẹ ńlá, o kíyèsí bọ́ọlù àyíká kan ní orí ilẹ, tí ó ní iṣẹ́ ọnà; ó sì jẹ́ ti idẹ tí ó dára. Nínú bọ́ọlù nã sì ni kẹ̀kẹ́ méjì wà; ọ̀kan sì tọ́ka sí ọ̀nà èyítí àwa yíò tọ̀ lọ sínú aginjù. Ó sì ṣe tí a kó jọ lákọ́pọ̀ àwọn ohun èyíkéyĩ tí àwa yíò gbé lọ sínú aginjù; àti gbogbo ìyókù àwọn ìpèsè tẹ́lẹ̀ èyí tí Olúwa ti fifún wa; a sì mu irúgbìn irú gbogbo tí a lè gbé lọ sínú aginjù. Ó sì ṣe tí a mú àwọn àgọ́ wa tí a sì lọ kúrò sínú aginjù, rékọjá odò Lámánì. Ó sì ṣe tí a rìn ìrìn-àjò fun ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́rin, o fẹ́rẹ̀ jẹ́ níhà agbedeméjì gũsù àti ìlà oòrùn gũsù, ni a sì tún pa àgọ́ wa sí; a sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Ṣésà. Ó sì ṣe tí a mú àwọn ọrún wa àti àwọn ọfà wa, a sì jáde lọ sínú aginjù láti pa onjẹ fún àwọn ìdílé wa; lẹ́hìn tí ti pa onjẹ fún àwọn ìdílé wa, a tún padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé wa ní aginjù, sí ibi Ṣésà. A sì tún jáde lọ ní aginjù, à ntẹ̀lé ìhà kannã, à ńtọ apákan aginjù tí ó lọ̣́rá jùlọ, èyí tí ó wà ní àwọn etí nítòsí Òkun Pupa. Ó sì ṣe tí a rin ìrìn-àjò fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀, à npa onjẹ lẹ́bã ọ̀nà, pẹ̀lú àwọn ọrún wa àti àwọn ọfà wa àti àwọn òkúta wa àti àwọn kànnà-kànnà wa. A sì tẹ̀lé àwọn ìhà bọọlu nã, èyítí ó tọ́ wa ní àwọn apákan aginjù tí o ní ọ̀rá jùlọ. Lẹ́hìn tí a sì ti rin ìrìn-àjó fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀, a pa àgọ́ wa fún ìwọ̀n ìgbà díẹ̀, kí àwa tún lè simi kí á sì ní onjẹ fún àwọn ìdílé wa. Ó sì ṣe tí, bí èmi, Nífáì, ti jáde lọ láti pa onjẹ, kíyèsĩ i, mo ṣẹ́ ọrun mi èyítí a fi irin tí ó dára ṣe; àti pé lẹhin tí mo ṣẹ́ ọrun mi, kíyèsĩ i, àwọn arákùnrin mi bínú sí mi nítori àdánù ti ọrun mi, nítorí a kò ní onjẹ. Ó sì ṣe tí a padà láìsí onjẹ sọ́dọ̀ àwọn ìdílé wa, nítorípé wọ́n sì ṣe ãrẹ̀ púpọ̀, nítorí ìrìn àjò wọn, wọ́n jìyà púpọ̀ nítorí àìní onjẹ. Ó sì ṣe tí Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì àti àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì bẹ̀rẹ̀sí kùn lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ìjìyà àti ìpọ́njú wọn ní aginjù; àti bàbá mi pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀sí kùn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀; bẹni, gbogbo wọn sì kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, gẹ́gẹ́bí wọn ti nkùn sí Olúwa. Nísisìyí ó ṣe tí èmi, Nífáì, nítorí tí mo ti rí ìpọ́njú pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi nítorí ti àdánù ọrun mi, àti nítorí tí àwọn ọrun wọn ti pàdánù nínà wọn, ó bẹ̀rẹ̀sí nira lọ́pọ̀lọpọ̀, bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí a kò lè rí onjẹ. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, sọ̀rọ̀ púpọ̀ sí àwọn arákùnrin mi, nítorí tí wọn tún ti sé àyà wọn le, àní tí wọ́n fi nráhùn sí Olúwa Ọlọ́run wọn. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, láti ara igi mo ṣe ọrun, àti ọfà láti ara igi tí kò wọ́; nítorí-èyi, mo gbé ara mí dì pẹ̀lú ọrun àti ọfà, pẹ̀lú kànnà-kànnà àti pẹ̀lú àwọn òkúta. Mo sì wí fún bàbá mi: Níbo ni èmi yíò lọ láti rí onjẹ? Ò sì ṣe tí ó bèrè lọ́wọ́ Olúwa, nítorí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀ nítorí ti àwọn ọ̀rọ̀ mi; nítorí mo sọ àwọn ohun púpọ̀ sí wọn ní okun-inú ọkàn mi. Ó sì ṣe tí ohùn Olúwa tọ bàbá mi wá; a sì bá a wí nítọ́tọ́ nítorí ti kíkùn rẹ̀ sí Olúwa, tóbẹ̃ tí a rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ sínú ìjìnlẹ̀ ìbànújẹ́. Ó sì ṣe tí ohùn Olúwa wí fún un: Yí ojú sórí bọ́ọ́lù ná à, kí o sì kíyèsĩ àwọn ohun èyí tí a kọ. Ó sì ṣe tí nígbàtí bàbá mi kíyèsĩ àwọn ohun èyí tí a kọ sórí bọ́ọ́lù ná à, ó bẹ̀rù ó sì wárìrì lọ́pọ̀lọpọ̀, àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì àti àwọn aya wa pẹ̀lú. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, kíyèsĩ àwọn afọ̀nàhàn èyí tí ó wà nínú bọ́ọ́lù ná à, tí wọ́n nṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ àti ãpọn àti ìṣọ́ra èyí tí a fifún wọn. Ìkọ̀wé titun ni a sì kọ sórí wọn pẹ̀lú, èyí tí ó ṣe kerekere láti kà, èyí tí ó fún wa ní ìmọ̀ nípa ti àwọn ọ̀nà Olúwa; a sì kọ ọ́ a sì yí i padà láti ìgbà dé ìgbà, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ àti ãpọn èyítí a fifún wọn. Báyĩ sì ni a rí i pé nípasẹ̀ ọ̀nà kékeré Olúwa lè mú àwọn ohun nlá wá. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, jáde sókè lọ sí orí òkè gíga, gẹ́gẹ́bí ìtọ́ sí ọ̀nà èyí tí a fún wa lórí bọọlu. Ó sì ṣe tí mo pa àwọn ẹranko ìgbẹ́, tóbẹ̃ tí mo rí onjẹ fún àwọn ìdílé wa. Ó sì ṣe tí mo padà sí àgọ́ wa, tí mo gbé àwọn ẹranko èyí tí mo ti pa; àti nísisìyí nígbàtí wọ́n kíyèsĩ i pé mo ti rí onjẹ, báwo ni ayọ̀ wọn ṣe pọ̀ tó! Ó sì ṣe tí wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, wọ́n sì fi opẹ́ fún un. Ó sì ṣe tí a tún mú ìrìn-àjò wa pọ̀n, tí à fẹ́rẹ̀ má a rìn ipa ọ̀nà kannã bí ti ìbẹ̀rẹ́ wá; lẹ́hìn tí a sì ti rin ìrìn-àjò fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀ a tún pa àwọn àgọ́ wa, kí á lè dúró lẹ́hìn fún ìwọ̀n ìgbà díẹ̀. Ó sì ṣe tí Íṣmáẹ́lì kú, tí a sì sin ín ní ibi èyí tí à npè ní Néhọ́mù. Ó sì ṣe tí àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì ṣọ̀fọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ti òfò ti bàbá wọn, àti nítorí ti ìpọ́njú wọn ní aginjù; wọ́n sì nkùn sí bàbá mi, nítorí ó ti mú wọn jáde wá láti ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, wọ́n nwípé: Bàbá wa ti kú; bẹ̃ni, a sì ti rìn kiri púpọ̀ ní aginjù, a sì ti faradà ìpọ́njú, ebi, òùngbẹ, àti ãrẹ̀ púpọ̀; lẹ́hìn gbogbo ìjìyàwọ̀nyí a ó sì ṣègbé ní aginjù pẹ̀lú ebi. Báyí sì ni wọ́n kùn sí bàbá mi, àti sí mi pẹ̀lú; wọ́n sì ní ìfẹ́ láti tún padà sí Jerúsálẹ́mù. Lámánì sì wí fún Lẹ́múẹ́lì àti pẹ̀lú fún àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì: Kíyèsĩ i, ẹ jẹ́kí á pa bàbá wa, àti arákùnrin wa Nífáì, ẹni tí ó fi fún ara rẹ̀ láti jẹ́ alákọ́so wa àti olùkọ́ wa, àwa tí a jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Nísisìyí, ó nwípé Olúwa ti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú òun, àti pẹ̀lú pé àwọn angẹ́lì ti ṣe ìránṣẹ́ fún òun. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, a mọ̀ pé ó npurọ́ fún wa; ó sì nsọ àwọn ohun wọ̀nyí, ó sì nṣe àwọn ohun púpọ̀ nípasẹ̀ àwọn ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, kí ó lè tan ojú wa jẹ, ó nronú, bóyá, pé òun lè tọ́ wa kúrò sínú aginjù àjèjì kan; lẹ́hìn tí ó bá sì ti tọ́ wa kúrò, ó ti ronú láti fi ara rẹ̀ ṣe ọba àti alákọ́so lórí wa, kí ó lè ṣe pẹ̀lú wa gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti fãjì rẹ̀. Ní ọ̀nà eleyĩ sì ni arákùnrin mi Lámánì ṣe rú ọkàn wọn sókè sí ìbínú. Ó sì ṣe tí Olúwa wà pẹ̀lú wa, bẹ̃ni, àní ohùn Olúwa wá ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ púpọ̀ sí wọn; ó sì bá wọn wí lọ́pọ̀lọpọ̀; lẹ́hìn tí a sì bá wọn wí nípasẹ̀ ohùn Olúwa wọ́n yí ìbínú wọn padà kuro, wọ́n sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tóbẹ̃ tí Olúwa tún bùkún wa pẹ̀lú onjẹ, tí àwa kò ṣègbé. 17 A pàṣẹ fún Nífáì láti kan ọkọ̀—Àwọn arákùnrin rẹ̀ takò ó—O gbà wọ́n níyànjú nípa ṣíṣe ìtúnsírò ìwé ìtàn ìbálò Ọlọ́run pẹ̀lú Ísráẹ́lì—Nífáì kún fún agbára Ọlọ́run—A ka a lẽwọ̀ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ láti fọwọ̀ kàn án, kí wọ́n má bà á rẹ̀ bí ifefe gbígbẹ. Ní ìwọ̀n ọdún 592 sí 591 kí á tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí a tún mú ìrìn-àjò wa pọ̀n sí aginjù; a rin ìrìn-àjò síhà tí ó fẹ́rẹ́ jẹ́ ìlà oòrùn láti ìgbà ná à lọ. A sì rin ìrìn-àjò, a sì fi ìṣòro rìn já ìpọ́njú púpọ̀ ní aginjù; àwọn obìnrin wa sì bí àwọn ọmọ ní aginjù. Títóbi báyĩ sì ni ìbùkún Olúwa lórí wa, pé nígbàtí ẹran tútù jẹ́ oúnjẹ wa ní aginjù, àwọn obìnrin wa fi ọpọ̀lọpọ̀ ọmú fún àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì lágbára, bẹ̃ni, àní dàbí àwọn ọkùnrin; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí faradà àwọn rínrin ìrìn-àjò wọn láìsí ìkùnsínú. Báyĩ ni a sì rí i pé àwọn òfin Ọlọ́run ni a gbọ́dọ̀ mú ṣẹ. Bí ó bá sì jẹ́ pé àwọn ọmọ ènìyàn npa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, ó nbọ́ wọn, ó sì nfún wọn ní agbára, ó sì npèsè ọ̀nà nípa èyí tí wọ́n lè ṣe ohun èyí tí ó ti pàṣẹ fún wọn parí; nítorí-èyi, ó pèsè ọ̀nà fún wa nígbàtí a ṣe àtìpó ní aginjù. A sì ṣe àtìpó fún ìwọ̀n ọdún púpọ̀, bẹ̃ni, àní ọdún méjọ ní aginjù. A sì dé ilẹ̀ èyí tí a pè ní Ibi-Ọ̀pọ̀, nítorí ti èso púpọ̀ rẹ̀ àti oyin ìgan pẹ̀lú; gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí sì ni Olúwa pèsè kí àwa má bà á ṣègbé. A sì kíyèsí òkun, èyí tí a pè ní Irreántúmì, èyí tí, ní ìtumọ́, jẹ́ omi púpọ̀. Ó sì ṣe tí a pa àwọn àgọ́ wa sí ẹ̀bá òkun; àti l’áiṣírò a ti jìyà ìpọ́njú púpọ̀ àti ìṣòro púpọ̀, bẹ̃ni, àní púpọ̀ gan an tí a kò lè kọ gbogbo wọn, a mú wa yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbàtí a dé ẹ̀bá òkun;a sì pe ibi ná à ní Ibi-Ọ̀pọ̀, nítorí ti èso púpọ̀ rẹ̀. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí èmi, Nífáì, ti wà ní ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀ fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀, ohùn Olúwa wá sọ́dọ́ mi, wípé: Dìde, kí o sì gun òkè gíga lọ. Ó sì ṣe tí mo dìde tí mo sì gòkè lọ sí òkè gíga, tí mo sì kígbe pe Olúwa. Ó sì ṣe tí Olúwa wí fún mi, wípé: Ìwọ yíò kan ọkọ̀ kan, ní ọ̀nà èyí tí èmi yíò fi hàn ọ́, kí emí kí ó lè kó àwọn ènìyàn rẹ rékọjá omi wọ̀nyí. Mo sì ní: Olúwa, níbo ni èmi yíò lọ kí èmi lè rí irin àìpò tútù láti yọ́, kí èmi lè ṣe àwọn ohun èlò láti kan ọkọ̀ ná à ní ọ̀nà èyí tí ìwọ ti fi hàn mí? O sì ṣe tí Olúwa sọ fún mí ibi tí èmi yíò lọ kí èmi lè rí irin àìpò tútù, kí èmi kí o lè ṣe àwọn ohun èlò. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, ṣe ẹwìrì kan pẹ̀lú èyí tí a ó fẹ́ iná ná à, ti awọ ara àwọn ẹranko; lẹ́hìn tí mo sì ti ṣe ẹwìrì, kí èmi lè ní nkan láti fẹ́ ina ná à, mo lu òkúta méjì mọ́ra kí èmi lè ṣe iná. Nítorí Olúwa títí di ìsisìyĩ kò ì tĩ gbà kí àwa kí ó ṣe iná púpọ̀, bí a ṣe nrin ìrìn-àjò ní aginjù; nítorí ó ní: Èmi yíò mú onjẹ yín di dídùn, tí ẹ̀yin kò ní sè é; Èmi yíò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ yín ní aginjù pẹ̀lú; èmi yíò sì pèsè ọ̀nà níwájú yín, bí ó bá ṣe pé ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́; nítorí-èyi, níwọ̀n bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́ a ó tọ́ yín síhà ilẹ̀ ìlérí; ẹ̀yin yíò sì mọ̀ pé nípasẹ̀ mi ni a fi tọ́ yín. Bẹ̃ni, Olúwa sì sọ pẹ̀lú pé: Lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti dé ilẹ̀ ìlérí, ẹ̀yin yíò mọ̀ pé èmi, Olúwa, ni Ọlọ́run; àti pé èmi, Olúwa, gbà yín lọ́wọ́ ìparun; bẹ̃ni, tí mo mú yín jáde wá láti ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù. Nítorí-èyi, èmi, Nífáì, gbìyànjú láti pa àwọn òfin Olúwa mọ́, mo sì gbà àwọn arákùnrin mi ní ìyànjú sí ìṣòtítọ́ àti ãpọn. Ó sì ṣe tí mo ṣe àwọn ohun èlò ní ti irin tútù tí mo yọ́ láti inú àpáta. Nígbàtí àwọn arákùnrin mi sì ríi pé mo ti fẹ́ má a kan ọkọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀sí kùn sí mi, wípé: Arákùnrin wa jẹ́ aṣiwèrè, nítorí ó rò pé òun lè kan ọkọ̀; bẹ̃ni, ó sì rò pẹ̀lú pé òun lè dá omi nlá wọ̀nyí kọjá. Báyĩ sì ni àwọn arákùnrin mi ráhùn sí mi, ti wọ́n sì nfẹ́ pé kí àwọn má lè ṣiṣé, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé mo lè kan ọkọ̀; bẹ̃ni wọn kò fẹ́ gbàgbọ́ pé a fi àṣẹ fún mi nípa ọwọ́ Olúwa. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ti líle ọkàn wọn; àti nísisìyí nígbàtí wọ́n ríi pé mo bẹ̀rẹ̀sí kún fún ìbànújẹ́ wọ́n yọ̀ ní ọkàn wọn, tóbẹ̃ tí wọ́n yọ̀ lórí mi, wípé: Àwa mọ̀ pé ìwọ kò lè kan ọkọ̀, nítorí àwa mọ̀ pé ìwọ ṣe aláìní òye; nítorí-èyi, ìwọ kò lè ṣe iṣẹ́ nlá báyĩ í parí. Ìwọ sì dàbí bàbá wa, tí a tọ́ kúrò nípasẹ̀ èrò aṣiwèrè ti ọkàn rẹ̀; bẹ̃ni, òun ti tọ́ wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, a sì ti sáko ní aginjù fún àwọn ọdún púpọ̀ wọ̀nyí; àwọn obìnrin wa sì ti ṣe lãlã, nítorí tí wọ́n tóbi fún oyún; wọ́n sì ti bí ọmọ ní aginjù; wọ́n sì jìyà ohun gbogbo, àfi ikú; ìbá sì ti dárajùkí wọ́n ti kú kí wọ́n tó jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù ju láti jìyà ìpọ́njù wọ̀nyí. Kíyèsĩ i, ní àwọn ọdún púpọ̀ wọ̀nyí àwa ti jìyà ní aginjù, àkókò èyí ti àwa ìbá ti gbádùn àwọn ìní wa àti ilẹ̀ ogún wa; bẹ̃ni, àwa ìbá sì ti ní inúdídùn. A sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù jẹ́ olódodo ènìyàn; nítorí wọ́n pa ìlànà àti ìdájọ́ Olúwa mọ́, àti gbogbo àṣẹ rẹ̀, gẹ́gẹ́bí òfin Mósè; nítorínã, àwa mọ̀ pé wọ́n jẹ́ olódodo ènìyàn; bàbá wa sì ti dá wọn léjọ́, ó sì ti tọ́ wa kúrò nítorí tí a fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀; bẹ̃ni, arákùnrin wa sì dàbí òun. Ní irú èdè báyĩ sì ni àwọn arákùnrin mi kùn tí wọ́n sì ráhùn sí wa. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, wí fún wọn, wípé: Ẹ̀yin ha gbàgbọ́ pé a lè tọ́ àwọn bàbá wa, tí wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ Isráẹ́lì, jáde kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Égíptì bí wọn kò bá fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa? Bẹ̃ni, ẹ̀yin ha ṣebí à bá ti lè tọ́ wọn jáde ní oko ẹrú, bí Olúwa kò bá pàṣẹ fún Mósè pé kí ó tọ́ wọn jáde ní oko ẹrú? Nísisìyí ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ọmọ Isráẹ́lì wa ní oko ẹrú; ẹ̀yin sì mọ̀ pé a di ẹrù lé wọn pẹ̀lú iṣẹ́, èyí tí o ṣòro láti rù; nítorí-èyi, ẹ̀yin mọ̀ pé ohun rere ni fún wọn ti o si di dandan, pé kí á mú wọn jáde ní oko ẹrú. Nísisìyí ẹ̀yin mọ̀ pé Olúwa pàṣẹ fún Mósè láti ṣe iṣẹ́ nlá nì; ẹ̀yin sì mọ̀ pé nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ àwọn omi Òkun Pupa ni a pín síhĩn àti sọ́hũn, wọ́n sì kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ará Égíptì rì sínú omi Òkun Pupa, tí wọ́n jẹ́ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Fáráò. Ẹ̀yin sì mọ̀ pẹ̀lú pe a fi mánnà bọ́ wọn ní aginjù. Bẹ̃ni, ẹ̀yin sì mọ̀ pẹ̀lú pé Mósè, nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí agbára Ọlọ́run èyí tí ó wà nínú rẹ̀, lu àpáta, omi sì jáde wá, kí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì lè pa òùngbẹ wọn. Àti l’áìṣírò à ntọ́ wọn, tí Olúwa Ọlọ́run wọn, Olùràpadà wọn, nlọ níwájú wọn, tí ó ntọ́ wọn ní ọ̀sán tí ó sì ńfi ìmọ́lẹ̀ fún wọn ní òru, tí ó sì ńṣe ohun gbogbo fún wọn èyí tí ó jẹ́ yíyẹ fún ènìyàn láti gbà, wọ́n sé ọkàn wọn le wọ́n sì fọ́ ojú inú wọn, wọ́n sì nkẹ́gàn Mósè àti Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè. Ó sì ṣe gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó pawọ́n run; ati gẹgẹbi ọrọ rẹ, otọ́ wọn; àti gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó ṣe ohun gbogbo fún wọn; kò sì sí ohun kóhun tí a ṣe bíkòṣe tí ó jẹ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti ré odò Jordánì kọjá ó ṣe wọ́n ní alágbára sí dídà sóde àwọn ọmọ ilẹ̀ nã, bẹ̃ni, sí títúká wọn sí ìparun. Àti nísisìyí, ẹ̀yin ha ṣebí àwọn ọmọ ilẹ̀ yí, tí ó wà ní ilẹ̀ ìlérí, tí a dà sóde nípasẹ̀ àwọn bàbá wa, ẹ̀yin ha ṣebí pé wọ́n jẹ́ olódodo? Kíyèsĩ i, mo wí fún yín, Bẹ̃kọ́. Ẹ̀yin ha ṣebí àwọn bàbá wa yíò ti jẹ́ àṣàyàn jùlọ jù wọ́n bí wọ́n bá ti jẹ́ olódodo? Mo wí fún yín, Bẹ̃kọ́. Kíyèsĩ i, Olúwa kà gbogbo ẹran ara sí ọ̀kan; ẹni tí ó bá jẹ́ olódodo yíò rí ojúrere Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, àwọn ènìyán yí ti kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì gbó nínú àìṣedẽdé; ẹkún ìbínúỌlọ́run sì wà lórí wọn; Olúwa sì fi ilẹ̀ nã bú sí wọn, ó sí bùkún fun àwọn bàbá wa; bẹ̃ni, ó fi bú sí wọn sí ìparun wọn, ó sì bùkún un fún àwọn bàbá wa sí gbígba agbára lórí rẹ̀. Kíyèsĩ i, Olúwa ti dá ayé pé kí á lè gbé inú rẹ̀; ó sì ti dá àwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n lè jogún rẹ̀. Ó sì gbé orílẹ̀-èdè olódodo dìde, ó sì pa àwọn orílẹ̀-èdè ènìyan búburú run. Ó sì tọ́ olódodo kúrò sínú àwọn ojúlówó ilẹ̀, ènìyàn búburú ni ó parun, ó sì fi ilẹ̀ bú sí wọn nítorí wọn. Ó jọba níbi gíga ní ọ̀run, nítorípé ó jẹ́ ìtẹ́ rẹ̀, ayé yí sì jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀. Ó sì fẹ́ràn àwọn tí ó bá fẹ́ ẹ láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Kíyèsĩ i, ó fẹ́ràn àwọn bàbá wa, ó sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, bẹ̃ni, àní Ábráhámù, Ísãkì, àti Jákọ́bù; ó sì rántí awọn májẹ̀mú èyítí ó ti ṣe; nítorí-èyi, ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Égíptì. Ó sì ni wọ́n lára ní aginjù pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀; nítorí wọ́n sé ọkàn wọn le, àní gẹ́gẹ́bí ẹ̀yin ti ṣe; Olúwa sì ni wọ́n lára nítorí àìṣedẽdé wọn. Ó rán àwọn ejò oníná tí nfò sí ãrín wọn; lẹ́hìn tí wọ́n sì ti bù wọ́n ṣán ó pèsè ọ̀nà kí a lè mú wọn lára dá; iṣẹ́ tí wọ́n sì ní láti ṣe ni láti wò; nítorí ti ìrọ̀rùn ọ̀nà nã, tàbí àìnira rẹ̀, ọ̀pọ̀ ni ó wà tí ó ṣègbé. Wọ́n sì sé ọkàn wọn le láti àkókò dé àkókò, wọ́n sì nkẹ́gàn Mósè, àti Ọlọ́run pẹ̀lú; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ẹ̀yin mọ̀ pé a tọ́ wọn jáde nípasẹ̀ agbára rẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ sí ilẹ̀ ìlérí. Àti nísisìyí, lẹ́hìn gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí, àkókò nã ti dé tí wọ́n ti di búburú, bẹ̃ni, ó kù díẹ̀ sí gbígbó; ó sì lè jẹ́ òtítọ́ pé ní ọjọ́ òní a ti fẹ́ pa wọ́n run; nítorí mo mọ̀ pé ọjọ́ nã yíò dé dájúdájú tí a ó pa wọ́n run, àfi àwọn díẹ̀ péré, tí a ó tọ́ kúrò sí ìgbèkun. Nítorí-èyi, Olúwa pàṣẹ fún bàbá mi pé kí ó lọ kúrò sínú aginjù; àwọn Jũ nã sì nwá láti mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ pẹ̀lú; bẹ̃ni, ẹ̀yin pẹ̀lú sì ti wá láti mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ; nítorí-èyi, ẹ̀yin jẹ́ apànìyàn ní ọkàn yín ẹ̀yin sì dábí àwọn. Ẹ̀yin yára láti ṣe àìṣedẽdé ṣùgbọ́n ẹ lọ́ra láti rántí Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ̀yin ti rí angẹ́lì kan, ó sì sọ̀rọ̀ sí yín; bẹ̃ni, ẹ̀yin ti gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àkókò dé àkókò; ó sì ti sọ̀rọ̀ sí yín ní ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kékeré, ṣùgbọ́n àyà yín le rékọjá, tí ẹ kò lé mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ lára; nítorínã, ó ti sọ̀rọ̀ sí yín tí ó dàbí sísán ãrá, èyí tí ó mú ayé láti mì bí ẹni pé yíò pínníyà. Ẹ̀yin sì mọ̀ pẹ̀lú pé nípasẹ̀ agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó lágbára jùlọ ó lè mú ayé kí ó rékọjá; bẹ̃ni, ẹ̀yin sì mọ̀ pé nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó lè mú àwọn ibi pálapàla láti di dídán, àwọn ibi dídán ni a ó sì fọ́. Njẹ́, nígbànã, ẽṣe, tí ẹ̀yin fi le báyĩ ní ọkàn yín? Kíyèsĩ i, ẹ̀mí mi ni a fà ya pẹ̀lú ìrora nítorí yín, ọkàn mi sì kẹ́dùn; mo bẹ̀rù kí á máṣe ṣá yín tì láéláé. Kíyèsĩ i, mo kún fún Ẹ̀mí Ọlọ́run, tóbéẹ̀ tí ara mi kò ní agbára. Àti nísisìyí sì ṣe pe nígbàtí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wọ́n bínú sí mi, wọ́n sì fẹ́ láti jù mí sínú ibú òkun; bí wọ́n sì ti wá síwájú láti gbé ọwọ́ lé mi mo wífún wọn, wípé: Ní orúkọ Ọlọ́run Olódùmarè, mo pàṣẹ fún yín kí ẹ máṣe fọwọ́ kàn mí, nítorí mo kún fún agbára Ọlọ́run, àní sí jíjẹ ẹran ara mi tán; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ọwọ́ lé mi yíò gbẹ àní bí ìye gbígbẹ; òun yíò sì jẹ́ bí asán níwájú agbára Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run yíò lù ú. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, wí fún wọn pé kí wọ́n máṣe kùn mọ́ sí bàbá wọn; bẹ̃ni wọn kò gbọ́dọ̀ dá iṣẹ́ wọn dúró fún mi, nítorí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún mi pé kí èmi kí ó kan ọkọ̀. Mo sì wí fún wọn: Bí Ọlọ́run bá ti pàṣẹ fún mi láti ṣe ohunkóhun èmi lè ṣe wọ́n. Bí ó bá pàṣẹ fún mi pé kí èmi kí ó wí fún omi yĩ, ìwọ di ilẹ̀, òun yíò di ilẹ̀; bí èmi bá sì sọ ọ́, a ó ṣe é. Àti nísisìyí, bí Olúwa bá ní irú agbára nlá nã, tí ó sì ti ṣe iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn, báwo ní òun kò ní lè fi àṣẹ fún mi, pé kí èmi kí ó kan ọkọ̀ kan? Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, sọ àwọn ohun púpọ̀ sí àwọn arákùnrin mi, tóbẹ̃ tí wọ́n dãmú tí wọn kò sì lè dọjú ìjà kọ mí; bẹ̃ni wọn kò gbọ́dọ̀ gbé ọwọ́ wọn lé mi tàbí kí wọ́n tọ́ mi pẹ̀lú àwọn ìka ọwọ́ wọn, àní fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀. Àti nísisìyí wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe eleyĩ kí wọ́n má bà á gbẹ níwájú mi, báyĩ ni Ẹ̀mí Ọlọ́run lágbára tó; báyĩ ni ó sì ti ṣe lórí wọn. Ó sì ṣe tí Olúwa wí fún mi: Na ọwọ́ rẹ jáde lẹ̃kejì sí àwọn arákùnrin rẹ, wọn kì yíò sì gbẹ níwájú rẹ, ṣùgbọ́n èmi yíò mú wọn wárìrì, ni Olúwa wí, èyí sì ni èmi yíò ṣe, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn. Ó sì ṣe tí mo na ọwọ́ mi jáde sí àwọn arákùnrin mi, tí wọn kò sì gbẹ níwájú mi; ṣùgbọ́n Olúwa mì wọ́n, àní gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ èyí tí ó ti sọ. Àti nísisìyí, wọ́n ní: Àwa mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pè Olúwa wà pẹ̀lu rẹ, nítorí àwa mọ̀ pé agbára Olúwa ni o mì wá. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú mi, wọ́n sì fẹ́ má a foríbalẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n èmi kò yọ̣́da fún wọn, mo ní: Mo jẹ́ arákùnrin yín, bẹ̃ni, àní arákùnrin àbúrò yín; nítorí-èyi, ẹ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sì bọ̀wọ̀ fún bàbá òun ìyá yín, kí ọjọ́ yín kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín yíò fi fún yín. 18 A parí ọkọ́ nã—A ṣe ìrántí ìbí Jákọ́bù àti Jósẹ́fù—Ọ̀wọ́ nã wọkọ̀ fún ilẹ̀ ìlérí—Àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì àti àwọn aya wọn dàpọ̀ ní àríyá-aláriwo àti ọ̀tẹ̀—A di Nífáì, ẹ̀fũfù nlá kan tí ó banilẹ́rù sì darí ọkọ̀ nã sẹ́hìn—A sọ Nífáì di ẹni òmìnira, nípasẹ̀ àdúrà rẹ̀ ìjì nã sì dáwọ́dúró—Àwọn ènìyàn nã dé ilẹ̀ ìlérí. Ní ìwọ̀n ọdún 591 sí 589 kí á tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí wọ́n foríbalẹ̀ fún Olúwa, tí wọ́n sì jáde lọ pẹ̀lú mi; a sì ṣe àwọn igi rírẹ́ ni aláràbarà iṣẹ́ ọnà. Olúwa sì nfi hàn mí láti àkókò dé àkókò bí èmi yíò ṣe ṣe àwọn igi rírẹ́ ọkọ̀ nã. Nísisìyí èmi, Nífáì, kò ṣe àwọn igi rírẹ́ nã bí èyí tí àwọn ènìyàn kọ́, ní ìkọ́ṣẹ́ bẹ̃ni èmi kò kan ọkọ̀ nã bí ti àwọn ènìyàn; ṣùgbọ́n mo kan bí èyí tí Olúwatí fi hàn sí mi; nítorí-èyi, kì í ṣe bí ti àwọn ènìyàn. Èmi, Nífáì, sì lọ sí òkè nígbà púpọ̀, mo sì gbàdúrà nígbà púpọ̀ sí Olúwa; nítorí-èyi Olúwa fi àwọn ohun nlá hàn sí mi. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí mo ti parí ọkọ̀ nã, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Olúwa, àwọn arákùnrin mi kíyèsĩ i pé ó dára, àti pé iṣẹ́ nã dára lọ́pọ̀lọpọ̀; nítorí-èyi, wọ́n tún rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Olúwa. Ó sì ṣe tí ohùn Olúwa sì tọ bàbá mi wá, pé kí á dìde kí á sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọkọ̀ nã. Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, lẹ́hìn tí a ti pèsè ohun gbogbo, àwọn èso púpọ̀ àti ẹran láti aginjù, àti oyin ní ọ̀pọ̀, àti ìpèsè sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí èyí tí Olúwa ti pàṣẹ fún wa, a sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọkọ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun wa tí a dì àti àwọn irú-ọmọ wa, àti ohun èyíkéyĩ tí a ti mú wá pẹ̀lú wa, olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́bí ọjọ́ orí rẹ̀; nítorí-èyi, gbogbo wa sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọkọ̀, pẹ̀lú àwọn aya wa àti àwọn ọmọ wa. Àti nísisìyí, bàbá mi ti bí àwọn ọmọkùnrin méjì ní aginjù; èyí ẹ̀gbọ́n ni a pè ni Jákọ́bù àti èyí àbúrò Jósẹ́fù. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí a ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọkọ̀, tí a sì mú pẹ̀lú wa àwọn ìpèsè-sílẹ̀ wa àti àwọn ohun èyí tí a pàṣẹ fún wa, a ṣí ọkọ̀ jáde sínú òkun, afẹ́fẹ́ sí ndarí wa jáde síhà ilẹ̀ ìlérí. Lẹ́hìn tí afẹ́fẹ́ sì ti darí wa jáde fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀, kíyèsĩ i, àwọn arákùnrin mi àti àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì àti àwọn aya wọn pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀sí ṣe àjọyọ̀ tó bẹ̃gẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí njó, tí wọ́n sì nkọrin, tí wọ́n sì ńsọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìwà àimòye púpọ̀, bẹ̃ni, àní tí wọ́n gbàgbé nípasẹ̀ agbára èwo ni a ti fi mú wọn wá síbẹ̀ nã; a gbé wọn sókè sí ìwà àimòye tí ó pàpọ̀jù. Èmi, Nífáì, sì bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀ kí Olúwa má bà á bínú sí wa, kí ó sì lù wá nítorí ti àìṣedẽdé wa, kí a gbé wa mì ní ibú òkun; nítorínã, èmi, Nífáì, bẹ̀rẹ̀sí sọ̀rọ̀ sí wọn pẹ̀lú ìwà pẹ̀lẹ́ púpọ̀; ṣùgbọ́n kíyèsĩ i wọ́n bínú sí mi, wọn wí pé: Àwa kò ní gbà kí arákùnrin àbúrò wa ṣe alákọ́so lórí wa. Ó sì ṣe tí Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì mú mi tí wọ́n sì dì mí pẹ̀lú okùn, wọ́n sì hùwà sí mi pẹ̀lú ìrorò púpọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa yọ̣́da rẹ̀, kí ó lè fi agbára rẹ̀ hàn jáde, sí mímú ọ̀rọ̀ rẹ̀ èyí tí ó ti sọ nípa àwọn ènìyàn búburú ṣẹ. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí wọ́n ti dì mí tóbẹ̃ tí èmi kò lè ṣípòpadà, ẹ̀rọ àyíká, èyí tí Olúwa ti pèsè, dáwọ́dúró láti ṣiṣẹ́. Nítorí-èyi, wọn kò mọ́ ibi ti o yẹ ki wọn kí ó tọ́ ọkọ̀, tóbẹ̃ tí ìjì nlá kan dìde, bẹ̃ni, ẹ̀fũfùlile nlá kan tí ó sì banilẹ́rù, ó sì darí wa sẹ́hìn lórí omi fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí fòyà lọ́pọ̀lọpọ̀ kí wọ́n má bà á rì sínú omi ní òkun; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọn kò tú mi sílẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrin, èyí tí a ti darí wa sẹ́hìn, ẹ̀fũfùlíle nã sì bẹ̀rẹ̀sí di kíkan lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó sì ṣe tí a fẹ́rẹ̀ ẹ́ gbé wa mì ní ibú òkun. Lẹ́hìn tí a sì ti darí wa sẹ́hìn lórí omi fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́rin, àwọn arákùnrin mi bẹ̀rẹ̀sí rí i pé ìdájọ́ Ọlọ́run wà lórí wọn, àti pé wọ́n kò le ṣe àìṣègbé àfi tí wọ́n bá ronúpìwàdà ní ti àìṣedẽdé wọn;nítorí-èyi, wọ́n wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì tú àwọn èdídì èyí tí ó wà ní àwọn ọrùn-ọwọ́ mi, sì kíyèsĩ i wọ́n ti wú lọ́pọ̀lọpọ̀; àti ọrùn-ẹsẹ̀ mi pẹ̀lú wú púpọ̀, nlá sì ni ẹ̀dùn èyí nã. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo yí ojú sí Ọlọ́run mi, mo sì yìn ín ní gbogbo ọjọ́ nã; èmi kò sì kùn sí Olúwa nítorí ti ìpọ́njú mi. Nísisìyí bàbá mi, Léhì, ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun sí wọn, àti pẹ̀lú sí àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì; ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, wọ́n nmí ìmíìkìlọ̀ púpọ̀ sí ẹnikẹ́ni tí ìbá fẹ́ sọ̀rọ̀ nítorí tèmi; àwọn òbí mi nítorí wọ́n sì ti di arúgbó, àti nítorí tí wọ́n ti faradà ìbànújẹ́ púpọ̀ nítorí ti àwọn ọmọ wọn, a mú wọ́n sọ̀kalẹ̀, bẹ̃ni, àní lórí ibùsùn àìsàn wọn. Nítorí ti ìbànújẹ́ àti ìkãnú púpọ̀ wọn, àti àìṣedẽdé àwọn arákùnrin mi, a mú wọn sùnmọ́ àní láti gbé wọn jáde kúrò ní àkókò yí láti pàdé Ọlọ́run wọn; bẹ̃ni, ewú orí wọn ni à ńbọ̀wá mu sọ̀kalẹ̀ láti dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀; bẹ̃ni, àní wọ́n súnmọ́ pé kí a jù wọ́n sínú isà òkú olómi pẹ̀lú ìbànújẹ́. Àti Jákọ́bù àti Jósẹ́fù pẹ̀lú, nítorí wọ́n jẹ́ ọmọdé, tí wọ́n ní àìní níti bíbọ́ púpọ̀, ni a mú kẹ́dùn nítorí ti ìpọ́njú ìyá wọn; àti pẹ̀lú aya mi, pẹ̀lú omijé àti àdúrà rẹ̀, àti pẹ̀lú àwọn ọmọ mi, kò mú ọkàn àwọn arákùnrin mi rọ̀ tí àwọn yíò tú mi sílẹ̀. Kò sì sí nkan àfi tí ó bá jẹ́ agbára Ọlọ́run, èyí tí ó dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìparun, ni ó lè mú ọkàn wọn rọ̀; nítorí-èyi, nígbà t í wọ́n r í i pé a t i ńbọ̀wá gbé wọn mì ní ibú òkun, wọ́n ronúpìwàdà ní ti ohun èyí tí wọ́n ti ṣe, tóbẹ̃ tí wọ́n tú mi sílẹ̀. Ó sì ṣe lẹhìn tí wọ́n ti tú mi sílẹ̀, mo mú ẹ̀rọ olùtọ́nisọ́nà nã, ó sì ṣiṣẹ́ níbi tí mo bá tí fẹ́ ẹ. Ó sì ṣe tí mo gbàdúrà sí Olúwa; lẹ́hìn tí mo sì ti gbàdúrà, afẹ́fẹ́ nã dáwọ́dúró, ìjì nã sì dáwọ́dúró, ìparọ́rọ́ nlá kan sì wà. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, tọ́ ọkọ̀ nã sí ọ̀nà, tí a tún ṣíkọ̀ síhà ilẹ̀ ìlérí. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí a ti ṣíkọ̀ fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀, a dé ilẹ̀ ìlérí nã; a sì jáde lọ sórí ilẹ̀ nã, a sì pa àwọn àgọ́ wa dó; a sì pè é ní ilẹ̀ ìlérí. Ó sì ṣe tí a bẹ̀rẹ̀sí ro ilẹ̀, a sì bẹ̀rẹ̀sí gbin àwọn irúgbìn; bẹ̃ni, a fi gbogbo àwọn irúgbìn wa bọnú ilẹ̀, èyí tí a ti mú wá láti ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù. Ó sì ṣe tí wọn hù lọ́pọ̀lọpọ̀; nítorí-èyi a bùkún wa ní ọ̀pọ̀. Ó sì ṣe tí a rí lórí ilẹ̀ ìlérí, bí a ṣe nrin ìrìn-àjò ní aginjù, pé àwọn ẹranko wà nínú àwọn igbó ni oríṣiríṣi, àti abo màlũ àti màlũ, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ẹṣin, àti ewúrẹ́ àti ewúrẹ́ ìgbẹ́, àti irú àwọn ẹranko ìgbẹ́ gbogbo, èyí tí ó wà fún ìlò àwọn ènìyàn. A sì rí irú irin àìpò tútù gbogbo, àti ti wúrà, àti ti fàdákà, àti ti bàbà. 19 Nífáì ṣe àwọn àwo ti irin àìpò tútù ó sì kọ ìwé ìtàn àwọn ènìyàn rẹ̀ sínú ìwé ìrántí—Ọlọ́run Ísráẹ́lì yíò wá ní ẹgbẹ̀ta ọdún láti ìgbà tí Léhì kúrò ní Jerúsálẹ́mù—Nífáì sọ nípa ìjìyà àti ìyà ìkànmọ́ àgbélẽbú Rẹ̀—Àwọn Jũ ni a ó kẹ́gàn tí a ó sì túká títí àwọn ọjọ́ ti ìkẹhìn, nígbàtí wọnyíò padà sọ́dọ̀ Olúwa. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí Olúwa pàṣẹ fún mi, nítorí-èyi mo ṣe àwọn àwo ti irin àìpò tútù kí èmi bá lè fín ìwé ìrántí àwọn ènìyàn mi sórí wọn. Sí orí àwọn àwo èyí tí mo sì ṣe ni mo fín ìwé ìrántí bàbá mi, àti pẹ̀lú àwọn írìn àjò wa ní aginjù, àti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ bàbá mi; àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ tèmi ni mo ti fín sórí wọn. Èmi kòsí mọ̀ ní àkókò tí mo ṣe wọ́n pé Olúwa yíò pàṣẹ fún mi láti ṣe àwọn àwo wọ̀nyí; nítorí-èyi, ìwé ìrántí bàbá mi, àti ìtàn ìdílé àwọn bàbá rẹ̀, àti ipa tí ó jùlọ ti àwọn ìṣe wa gbogbo ní aginjù ni a fín sórí àwọn àwo ìṣãjú wọnnì nípa èyí tí mo ti sọ̀rọ̀; nítorí-èyi, àwọn ohun èyí tí o sẹlẹ̀ kí èmi tó ṣe àwọn àwo wọ̀nyí ni, ní òtítọ́, a ṣe ìrántí ní pàtàkì jùlọ sórí àwọn àwo ìṣãjú. Lẹ́hìn tí mo sì ti ṣe àwọn àwo wọ̀nyí nípasẹ̀ ọ̀nà àṣẹ, èmi, Nífáì, gba àṣẹ pé iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀, àwọn apákan wọn tí ó rí kerekere tí ó sì níyelórí jùlọ, ni a ó kọ sórí àwọn àwo wọ̀nyí; àti pé àwọn ohun èyítí a ó kọ ni a ó tọ́jú fún ẹkọ́ àwọn ènìyàn mi, tí yíò jogún ilẹ̀ nã, àti pẹ̀lú fún àwọn èté ọlọgbọ́n míràn, àwọn èté èyí tí ó jẹ́ mímọ̀ sí Olúwa. Nítorí-èyi, èmi, Nífáì, ṣe ìwé ìrántí kan sórí awọn àwo míràn nì, èyí tí ó fún ni ní ìṣirò, tàbí èyí tí ó fún ni ní ìṣirò tí ó tóbijù ti àwọn ogun àti àwọn ìjà àti àwọn ìparun àwọn ènìyàn mi. Èyí ni mo sì ti ṣe, tí mo sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn mi ohun tí wọn yíò ṣe lẹ́hìn tí èmi bá ti lọ; àti pé àwọn àwo wọ̀nyí ni kí á fi lé lẹ̀ láti ìran kan dé òmíràn, tàbí láti ọwọ wòlĩ kan dé òmíràn, títí di ìgbà tí a ó gba àwọn-ofin Olúwa. Ìṣirò ṣíṣe mi ti àwọn àwo wọ̀nyí ni a ó sì fi fún ni lẹ́hìn èyí; nígbànã sì ni, kíyèsĩ i, èmi tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́bí ti èyí tí mo ti sọ; èyí sì ni mo ṣe kí á lè tọ́jú àwọn ohun mímọ́ jùlọ fún ìmọ̀ àwọn ènìyàn mi. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi kò kọ ohunkóhun sórí àwọn àwo àfi eyi tí mo rò pé o jẹ́ mímọ́. Àti nísisìyí, bí mo bá sì ṣe àṣìṣe, àní bẹ̃gẹ́gẹ́ wọ́n ṣe àṣìṣe ní àtijọ́; kì í ṣe pé èmi yíò ṣe gáfárà fún ara mi nítorí ti àwọn ènìyàn míràn, ṣùgbọ́n nítorí ti àìlera èyí tí ó wà nínú mi, nípa ti ara, èmi yíò ṣe gáfárà fún ara mi. Nítorí àwọn ohun èyí tí àwọn ènìyàn kan kà sí pé ó jẹ́ iye nlá, àti sí ara àti ọkàn, àwọn míràn mu ní asán tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ wọn tẹ̀ mọ́lẹ̀. Bẹ̃ni, àní Ọlọ́run Isráẹ́lì gan-an ni àwọn ènìyàn nfi ẹsẹ̀ wọn tẹ̀ mọ́lẹ̀; mo ní, fi ẹsẹ̀ wọn tẹ̀ mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n èmi yíò sọ̀rọ̀ ní gbólóhùn míràn—wọ́n mu u ní asán, wọ́n kò sì fetísílẹ̀ sí ohùn ìmọ̀ràn rẹ̀. Sì kíyèsĩ ó mbọ̀wá, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ ángẹ́lì nã, ní ẹgbẹ̀ta ọdún láti ìgbà tí bàbá mi kuro ní Jerúsálẹ́mù. Aráyé, nítorí ti àìṣedẽdé wọn, yíò sì ṣe ìdájọ́ fún un bí ohun asán; nítorí-èyi wọ́n nà á, ó sì yọ̣́da rẹ̀; wọ́n sì lù ú, ó sì yọ̣́da rẹ̀. Bẹ̃ni, wọ́n tutọ́ sórí rẹ̀, ó sì yọ̣́da rẹ̀, nítorí ti ọ́re rẹ̀ tí ó nífẹ́ àti ìpamọ́ra rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn. Ọlọ́run àwọn bàbá wa, tí a tọ́ jáde ní Égíptì, jáde ní oko ẹrú, àti pẹ̀lú tí a pamọ́ ní aginjù nípa ọwọ́ rẹ̀, bẹ̃ni, Ọlọ́run Ábráhámù, àti ti Ísãkì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù, yọ̣́da ara rẹ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ angẹ́lì nã, bí ènìyàn, sí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, láti gbé e sókè, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ Sénọ́kì, àti láti kàn án mọ́ àgbélèbú, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ Néọ́mì, àti láti sìnkú rẹ̀ ní isà-òkú, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ Sénọ́sì, èyí tí ó sọ nípa ọjọ́ òkùnkùn mẹ́ta, èyí tí yíò jẹ́ àmì ikú rẹ̀ tí a fi fún àwọn tí yíò gbé inú erékùṣù òkun, ní pãpã jùlọ tí a fi fún àwọn tí ó jẹ́ ará ilé Isráẹ́lì. Nítorí báyĩ ni wòlĩ nã sọ: Olúwa Ọlọ́run dájúdájú yíò bẹ gbogbo ará ilé Isráẹ́lì wo ní ọjọ́ nì, àwọn kan pẹ̀lú ohùn rẹ̀, nítorí ti òdodo wọn, sí ayọ̀ nlá àti ìgbàlà wọn, àti àwọn míràn pẹ̀lú àrá àti mànàmáná agbára rẹ̀, nípasẹ̀ ẹ̀fũfù líle, nípasẹ̀ iná, àti nípasẹ̀ ẽfín, àti ìkũkù òkùnkùn, àti nípasẹ̀ ìṣísílẹ̀ ayé, àti nípasẹ̀ àwọn òkè gíga èyí tí a ó gbé sókè. Gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí kò sì lè ṣe àìwá wá dájúdájú, ni wòlĩ Sénọ́sì wí. Àwọn àpáta ayé kò sì lè ṣe àìfàya; nítorí ti ìkérora ayé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọba erékùṣù òkun sì ni Ẹ̀mí Ọlọ́run yíò ṣiṣẹ́ lé lórí, láti kígbe sókè: Ọlọ́run ẹ̀dá ohun gbogbo jìyà. Bí ó sì ṣe ti àwọn tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, ni wòlĩ nã wí, a ó nà wọ́n lẹ́gba ní ọwọ́ gbogbo ènìyàn, nítorí tí wọ́n kan Ọlọ́run Isráẹ́lì mọ́ àgbélẽbú, wọ́n sì yí ọkàn wọn sí ápákan, wọ́n nkọ àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu sílẹ̀, àti agbára àti ògo Ọlọ́run Isráẹ́lì. Nítorí tí wọ́n sì yí ọkàn wọn si ápákan, ni wòlĩ nã wí, tí wọ́n sì ti kẹ́gàn Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, àwọn yíò rìn kiri lóde ara, wọn ó sì ṣègbé, wọn ó sì di òṣé àti ìfiṣẹ̀sín, a ó sì kórìra wọn lãrín gbogbo orílẹ-èdè. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nígbàtí ọjọ́ ni bá dé, ni wòlĩ nã wí, tí wọn kò yí ọkàn wọn si ápákan kúrò níwájú Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, nígbànã ni òun yíò rántí awọn májẹ̀mú èyí tí ó ti ṣe sí àwọn bàbá wọn. Bẹ̃ni, nígbànã ni òun yíò rántí àwọn erékùṣù òkun; bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì, ni èmi yíò kójọ sínú, ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ wòlĩ Sénọ́sì, láti igun mẹ́rẹ̀rin ayé. Bẹ̃ni, gbogbo ayé ni yíò sì rí ìgbàlà Olúwa, ni wòlĩ nã wí; olúkúlùkù orílẹ̀-èdè, ìbàtan, èdè àti ènìyàn ni a ó bùkún fun. Èmi, Nífáì, sì ti kọ àwọn ohun wọ̀nyí sí àwọn ènìyàn mi, pé bóyá mo lè yí wọn lọ́kàn padà kí wọ́n lè rántí Olúwa Olùràpadà wọn. Nítorí-èyi, mo sọ̀rọ̀ sí gbogbo ará ilé Isráẹ́lì, bí o bá jẹ́ pé àwọn yíò gba àwọn ohun wọ̀nyí. Nítorí kíyèsĩ i, mo ní àwọn iṣẹ́ ninu ẹ̀mí, èyí tí ó mú mi láarẹ̀ àní tí gbogbo oríkẽ mi jẹ́ aláìlágbára, fún àwọn tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù; nítorí ìbá ṣe pé Olúwa ko ni áanú, láti fi hàn sí mi nípa wọn, gẹ́gẹ́bí ó ti ṣe sí àwọn wòlĩ ti àtijọ́, èmi ì bá ti ṣègbé pẹ̀lú. Dájúdájú òun sì fi hàn sí àwọn wòlĩ àtijọ́ ohun gbogbo nípa wọn; àti pẹ̀lú ó fi hàn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nípa wa; nítorí-èyi,o di dandan pe ki a mọ̀ nípa wọn nítorí a kọ wọ́n sórí àwọn àwo idẹ. Nísisìyí, ó ṣe tí èmi, Nífáì, kọ́ àwọn arákùnrin mi ní ẹ̀kọ́ àwọn ohun wọ̀nyí; ó sì ṣe tí mo ka ohun púpọ̀ sí wọn, èyí tí a fín sórí àwọn àwo idẹ, ki wọ́n lè mọ̀ nípa àwọn ohun tí Olúwa ńṣe ní àwọn ilẹ̀ míràn, lãrín àwọn ènìyàn ti àtijọ́. Mo sì ka ohun púpọ̀ sí wọn èyí tí a kọ sínú àwọn ìwé Mósè; ṣùgbọ́n ki emí lè yí wọn lọ́kàn padà ní kíkún jùlọ láti gbàgbọ́ nínú Olúwa Olùràpadà wọn mo ka sí wọn ohun tí wòlĩ Isaiah kọ; nítorí mo fi gbogbo ìwé-mímọ́ wé wa, kí ó lè wà fún ànfàní àti ẹ̀kọ́ wa. Nítorí-èyi mo wí fún wọn, wípé: Ẹ tẹ́tísí àwọn ọ̀rọ̀ wòlĩ nã, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ìyókù ará ilé Isráẹ́lì, ẹ̀ka tí ó ti ṣẹ́ kúrò; ẹ tẹ́tísí àwọn ọ̀rọ̀ wòlĩ, èyí tí a kọ sí gbogbo ará ilé Isráẹ́lì, kí ẹ sì fi wọ́n wé ara yín, kí ẹ̀yin lè ní ìrètí gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin yín lọ́dọ̀ àwọn tí ẹ̀yin ti ṣẹ́ kúrò; nítorí ní ọ̀nà yí ni wòlĩ nã ti kọ̀wé. 20 Olúwa fi àwọn èté rẹ̀ hàn sí Isráẹ́lì—A ti yan Isráẹ́lì nínú ìlérú ìpọ́njú, yíò sì jáde lọ kúrò ní Bábílọ́nì—Fi wé Isaiah 48. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa. Fetísílẹ̀ kí ẹ sì gbọ́ èyí, A! ilé Jákọ́bù, ẹ̀yin tí à nfi orúkọ Isráẹ́lì pe, tí ó sì ti inú omi Júdà wọnnì jáde wá, tàbí ti inú omi ìrìbọmi wá, tí ó nfi orúkọ Olúwa búra, tí ó sì ndárúkọ Ọlọ́run Isráẹ́lì, síbẹ̀síbẹ̀ wọn kò búra ní òtítọ́ tàbí ní òdodo. Bíótilẹríbẹ̃, wọ́n npe ara wọn ní ti ìlú mímọ́ nì, ṣùgbọ́n wọn kò gbé ara wọn lé Ọlọ́run Isráẹ́lì, ẹni tí o jẹ́ Olúwa àwọn Ọmọ-ogun; bẹ̃ni, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. Kíyèsĩ i, èmi ti kéde ohun ti ìṣãjú wọnnì láti ìpilẹ̀sẹ̀; wọ́n sì jáde lọ láti ẹnu mi, mo sì fi wọ́n hàn. Èmi fi wọ́n hàn lójijì. Èmi sì ṣe é nítorí mo mọ̀ pé olórí-líle ni ìwọ, ọrùn rẹ sì jẹ́ iṣan irin, àti iwájú rẹ idẹ; Mo sì tilẹ̀ ti kede fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wa; kí ó tó ṣẹlẹ̀ ni èmi ti fi wọ́n hàn ọ́; èmi sì fi wọ́n hàn kí ìwọ má bà á wípé—òrìṣà mi ni ó ṣe wọ́n, àti ère mi gbígbẹ́, àti ère mi dídà ni ó ti pàṣẹ fún wọn. Ìwo sì ti rí, ati ti o si gbọ gbogbo ohun yi; ìwọ ki yíò sì ha kede wọ́n? Àti pé èmi ti fi awọn ohun titun hàn ọ́ láti ìgbà yí lọ, àní awọn ohun tí ó pamọ, ìwọ ko sì mọ̀ wọ́n. A dá wọn nísisìyí, kì í sì ṣe ni àtètèkọ́ṣe, àní ṣãjú ọjọ́ tí ìwọ kò gbọ́ wọn a kede wọ́n fún ọ, kí ìwọ má bà á wípé—Kíyèsĩ i èmi mọ̀ wọ́n. Bẹ̃ni, ìwọ kò sì gbọ́; bẹ̃ni, ìwọ kò mọ̀; bẹ̃ni, láti ìgbà nã etí rẹ kò ṣí; nítorí tí èmi mọ̀ pè íwọ yíò hùwà àrékérekè gan-an, a sì pè ọ ní olùrékọjá láti inú wá. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nítorí orúkọ mi èmi ó mú ìbínú mi pẹ́, àti nítorí ìyìn mi, èmi o fàsẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ, kí èmi má bà á ké ọ kúrò. Nítorí, kíyèsĩ i, èmi ti tún ọ́ dá, èmi ti yàn ọ nínú iná ìlérú ìpọ́njú. Nítorí èmi tìkárãmi, bẹ̃ni, nítorí èmi tìkárãmi ni èmi yíò ṣe èyí, nítorí èmi kì yíò jẹ́ kí á bá orúkọ mi jẹ́, èmi kì yíò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn. Fetísílẹ̀ sí mi, A! Jákọ́bù, àti Isráẹ́lì ẹni-ìpè mi, nítorí èmi nã ni; èmi ni ẹni-ìkíní, èmi sì ni ẹni-ìkẹhìn pẹ̀lú. Ọwọ́ mi ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ pẹ̀lú, àtẹ́lewọ́ ọ̀tún mi sì ti na àwọn ọ̀run. Mo pè wọ́n, wọ́n sì jùmọ̀ dìde dúró. Gbogbo yín, ẹ péjọ, ẹ sì gbọ́; tani nínú wọn tí ó ti sọ nkan wọ̀nyí sí wọn? Olúwa ti fẹ́ ẹ; bẹ̃ni, òun yíò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ èyí tí ó ti kéde nípasẹ̀ wọn; òun yíò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Bábílọ́nì, apá rẹ̀ yíò sì wá sí órí àwọn ará Káldéà. Bẹ̃gẹ́gẹ́, ni Olúwa wí; èmi Olúwa, bẹ̃ni, èmi ti sọ̀rọ̀; bẹ̃ni, èmi ti pẽ láti kede, èmi ti mú u wá, òun yíò sì mú ọ̀nà rẹ̀ ṣe dẽdé. Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi; èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀; láti ìpílẹ̀sẹ̀, láti ìgbà tí a ti kéde rẹ̀ ni èmi ti sọ ọ́; Olúwa Ọlọ́run àti Ẹ̀mí rẹ̀, ni ó rán mi. Báyĩ s ì ni Olúwa wí, Olùràpadà rẹ, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì; èmi ti rán an, Olúwa Ọlọ́run rẹ ẹni tí ó kọ́ ọ láti jèrè, ẹni tí o tọ́ ọ ní ọ̀nà tí ó yẹ kí ìwọ lọ, ti ṣe é. A! ìbá ṣe pé ìwọ fi etí sí awọn òfin mi—nígbànã ni àlãfíà rẹ ìbá dàbí odò, àti òdodo rẹ bí àwọn ìgbì-omi òkun. Irú-ọmọ rẹ pẹ̀lú ìbá dàbí iyanrìn; ọmọ-bíbí inú rẹ bí tãrá rẹ̀; a kì bá ti ké orúkọ rẹ̀ kúrò tabi párun níwájú mi. Ẹ jáde kúrò ní Bábílọ́nì, ẹ sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará Káldéà, pẹ̀lú ohùn orin ẹ kede, sọ èyí, sọ́ jáde títí dé òpin ayé; ẹ wípé: Olúwa ti ra Jákọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ padà. Òungbẹ kò sì gbẹ wọ́n; ó mú wọn la aginjù wọnnì já; ó mú omi ṣàn jáde láti inú àpáta fún wọn; ó sán àpáta pẹ̀lú, omi sì tú jáde. Àti l’áìṣírò ó ti ṣe gbogbo èyí, àti èyítí ó tóbijũ pẹ̀lú, àlãfíà kò sí, ni Olúwa wí, fún àwọn ènìyàn búburú. 21 Messia nì yíò jẹ́ ìmọ́lè fún àwọn Kèfèrí, yíò sì sọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n di òmìnira—A ó kó Isráẹ́lì jọ pẹ̀lú agbára ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn—Àwọn ọba ni yíò jẹ́ àwọn bàbá olùtójú wọn—Fi wé Isaiah 49. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa. Àti lẹ̃kansĩ: Fetísílẹ, A! Ìwọ ará ilé Isráẹ́lì, gbogbo ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ kúrò tí a sì ti lé sóde nítorí ti ìwà búburú àwọn olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi; bẹ̃ni, gbogbo ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ kúrò, tí a ti túká sẹ́hìn odi, tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn mi, A! Ìwọ ará ilé Isráẹ́lì. Ẹ gbọ́ ti èmi, ẹ̀yin erékùṣù; kí ẹ sì fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn láti ọ̀nà jíjìn wá; Olúwa ti pè mí láti inú wá; láti inú ìyá mi ni ó ti dá orúkọ mi. Ó sì ti ṣe ẹnu mi bí idà mímú; nínú òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́, ó sì sọ mí di ọfà dídán; nínú apó rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́; Ó sì wí fún mi pé: Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi, A! Isráẹ́lì, nínú ẹni tí a ó yìn mí lógo. Nígbànã ni mo wípé, èmi ti ṣiṣẹ́ lásán, èmi ti lo agbára mi lófò àti lásán; nítọ́tọ́ ìdájọ́ minbẹ lọ́dọ̀ Olúwa, àti iṣẹ́ mi lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi. Àti nísisìyí, ni Olúwa wí— ẹni tí ó mọ́ mí láti inú wá kí èmi lè ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, láti mú Jákọ́bù padà wá sọ́dọ̀ rẹ̀—bíótilẹ̀jẹ́pé a lè má ṣa Isráẹ́lì jọ, síbẹ̀ èmi yíò ní ògo lójú Olúwa, Ọlọ́run mi yíò sì jẹ́ agbára mi. Ó sì wípé: Ó jẹ́ ohun kékeré kí ìwọ ṣe ìránṣẹ́ mi láti gbé àwọn ẹ̀yà Jákọ́bù dìde, àti láti mú àwọn ìpamọ́ Isráẹ́lì padà. Èmi yíò fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn Kèfèrí wípé kí ìwọ kí ó lè ṣe ìgbàlà mi títí dé ìkangun ayé. Báyĩ ni Olúwa, Olùràpadà Isráẹ́lì, Ẹní Mímọ́ rẹ̀ wi, fún ẹni tí ènìyàn ngàn, fún ẹni tí àwọn orílẹ̀-èdè kórìra, fún ìránṣẹ́ àwọn olórí: Àwọn ọba yíò rí, wọ́n ó sì dìde, àwọn ọmọ-aládé pẹ̀lú yíò foríbalẹ̀, nítorí Olúwa tí íṣe olóotọ́. Báyĩ ni Olúwa wí: Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, èmi ti gbọ́ tìrẹ, A! ẹ̀yin erékùṣù òkun, àti ní ọjọ́ ìgbàlà mo ti ràn ọ́ lọ́wọ́; èmi yíò sì pa ọ́ mọ́, èmi ó sì fi ìwọ ìránṣẹ́ mi ṣe májẹ̀mú àwọn ènìyàn, láti fi ìdí ayé múlẹ̀, láti mú ni jogún àwọn ahoro ilẹ̀ ìní; Kí ìwọ kí ó lè wí fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n: Ẹ jáde lọ; fún àwọn tí ó jókò ní òkùnkùn: Ẹ fí ara yín hàn. Wọn ó jẹ ní ọ̀nà wọnnì, pápá ìjẹ wọn yíò sì wà ní gbogbo ibi gíga. Ebi kì yíò pa wọ́n tàbí kí òùngbẹ gbẹ wọ́n, bẹ̃ni ọ́ru tàbí ọ́rùn kì yíò sì pa wọ́n; nítorí ẹni tí ó ti ṣe ãnú fún wọn yíò tọ́ wọn, àní níhà ìsun omi ni yíò ṣe amọ̀nà wọn. Èmi yíò sì sọ gbogbo àwọn òkè gíga mi wọnnì di ọ̀nà, a ó sì gbé àwọn ọ̀nà òpópó mi wọnnì ga. Àti nígbànã, A! ará ilé Isráẹ́lì, kíyèsĩ i, àwọn wọ̀nyí yíò wá láti ọ̀nà jíjìn, sì wò ó, àwọn wọ̀nyí láti àríwá wá àti láti ìwọ̀-oòrùn wá; àti àwọn wọ̀nyí láti ilẹ̀ Sínímù wá. Kọrin, A! ẹ̀yin ọ̀run; kí o sì yọ̀, A! ìwọ ayé; nítorí ẹsẹ̀ àwọn tí ó wà ní ìlà-oòrùn ni a ó fi múlẹ̀; sì bú jáde nínú orin kíkọ, A! ẹ̀yin òkè gíga; nítorí a kò ní lù wọ́n pa mọ́; nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rè nínú, yíò sì ṣe ãnú fún àwọn olùpọ́njú rẹ̀. Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ i, Síónì ti wípé: Olúwa ti kọ̀ mí silẹ̀, Olúwa mi sì ti gbàbgé mi—ṣùgbọ́n òun yíò fi hàn pé òun kò tí ì ṣe bẹ̃. Nítorí obìnrin ha lè gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ bí, tí kì yíò fi ṣe ìyọ́nú sí ọmọ inú rẹ̀? Bẹ̃ni, wọ́n lè gbàgbé, síbẹ̀ èmi kì yíò gbàgbé rẹ, A! ará ilé Isráẹ́lì. Kíyèsĩ i, èmi ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi; àwọn odi rẹ ńbe títílọ níwájú mi. Àwọn ọmọ rẹ yíò yára dojúkọ àwọn olùparun rẹ; àwọn tí ó fi ọ́ ṣòfò yíò sì ti ọ̀dọ̀ rẹ jáde. Gbé ojú rẹ sókè yí kákiri kí o sì kíyèsĩ i; gbogbo àwọn wọ̀nyí kó ara wọn jọ, wọn yíò sì wá sí ọ́dọ̀ rẹ. Bí mo sì ti wà, ni Olúwa wí, dájúdájú ìwọ ó fi gbogbo wọn bò ara rẹ, bí ohun ọ̀ṣọ́, ìwọ ó sì há wọn mọ́ ara àní bí ìyàwó. Nítorí ibi òfò àti ibi ahoro rẹ̀ wọnnì, àti ilẹ̀ ìparun rẹ, yíò tilẹ̀ há jù nísisìyí nítorí àwọn tí ngbé inú wọn; àwọn tí ó gbé ọ mì yíò sì jìnà réré. Àwọn ọmọ tí ìwọ yíò ní, lẹ́hìn tí ìwọ bá ti sọ ti ìsãjú nù, ní etí rẹ yíò tún wípé: Àyè nã há pọ̀jù fún mi; fi àyè fún mi kí èmi lè gbé. Nígbànã ni ìwọ yíò wí ní ọkàn rẹ pé: Tani ó bí àwọn wọ̀nyí fún mi, nítorí mo ti ṣòfò àwọn ọmọ mi, tí mo sì di ahoro, ìgbèkun, tí mo sì nṣí lọ ṣí bọ̀? Tani ó sì ti tọ́ àwọn wọ̀nyí dàgbà? Kíyèsĩ i, a fi èmi nìkan sílẹ̀; àwọn wọ̀nyí, níbo ni wọ́n ha ti wà? Báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsĩ i, èmi yiò gbé ọwọ́ mi sókè sí àwọn Kèfèrí, èmi ó sì gbé ọ̀págún mi sókè sí àwọn ènìyàn; wọn yíò sì gbé àwọn ọmọkùnrin rẹ wá ní apá wọn, a ó sì gbé àwọn ọmọbìnrin rẹ ní èjìká wọn. Àwọn ọba yíò jẹ́ bàbá olùtọ́jú rẹ, àti àwọn ayaba wọn yíò sì jẹ́ ìyá olùtọ́jú rẹ; wọn yíò tẹríba fún ọ ní ìdojúbolẹ̀, wọn ó sì lá ekuru ẹsẹ̀ rẹ; ìwọ yíò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa; nítorí ojú kì yíò ti àwọn tí ó bá dúró dè mí. Nítorí a ha lè gba ìkógun lọ́wọ́ alágbára bí, tàbí àwọn ondè lọ́wọ́ àwọn ẹni tí wọ́n tọ́ fún? Ṣùgbọ́n báyĩ ni Olúwa wí, a ó tilẹ̀ gba àwọn ondè kúrò lọ́wọ́ àwọn alágbára, a ó sì gba ìkógun lọ́wọ́ àwọn ẹni-ẹ̀rù; nítorí èmi yíò bá a jà ẹni tí ó bá bá ọ jà, èmi yíò sì gba àwọn ọmọ rẹ là. Èmi yíò sì bọ́ àwọn tí ó ni ọ́ lára pẹ̀lú ẹran ara wọn; wọn ó mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn ní àmuyó bí ọtíwáínì dídùn; gbogbo ẹran-ara yíò sì mọ̀ pé èmi, Olúwa, ni Olùgbàlà rẹ àti Olùràpadà rẹ, Ẹni Alágbára ti Jákọ́bù. 22 A ó tú Isráẹ́lì ká sórí gbogbo ojú àgbáyé—Àwọn Kèfèrí yíò tọ́jú, wọ́n ó sì bọ́ Isráẹ́lì pẹ̀lú ìhìn-rere ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn—A ó kó Isráẹ́lì jọ a ó sì gbà á là, àwọn ènìyàn búburú yíò sì jóná bí àkékù koríko—Ìjọba èṣù ni a ó parun, Sátánì ni a ó sì dè. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí èmi, Nífáì, ti ka àwọn ohun wọ̀nyí èyí tí a fín sórí àwọn àwo idẹ, àwọn arákùnrin mi wá sọ́dọ̀ mi wọ́n sì wí fún mi: Kíni àwọn ohun wọ̀nyí túmọ̀ sí èyí tí ìwọ ti kà? Kíyèsĩ i, ṣé kí á mọ̀ wọn gẹ́gẹ́bí àwọn ohun ti ẹ̀mí, èyí tí mbọ̀ wá kọjá gẹ́gẹ́bí ti ẹ̀mí tí kì í ṣè ti ẹran ara? Èmi, Nífáì, sì wí fún wọn: Kíyèsĩ i a fi wọ́n hàn si wòlĩ nì nípasẹ̀ ohùn ti Ẹ̀mí; nítorí nípasẹ̀ Ẹ̀mí ni a fi sọ ohun gbogbo di mímọ̀ fún àwọn wòlĩ, èyí tí yíò wá sórí àwọn ọmọ ènìyàn gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara. Nítorí-èyi, àwọn ohun nã nípa èyí tí mo ti kà jẹ́ àwọn ohun tí n ṣe ti ayé yí àti ti ẹ̀mí; nítorí ó ṣe bíẹnipé, bí ó pẹ́ bí ó yá, a ó tú ará ilé Isráẹ́lì ká sórí gbogbo ojú àgbáyé, àti pẹ̀lú lãrín gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Sì kíyèsĩ i, ọ̀pọ̀ ni ó wà tí ó ti sọnù nísisìyí kúrò ní ìmọ̀ àwọn wọnnì tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù. Bẹ̃ni, ipa tí ó jùlọ ti gbogbo àwọn ẹ̀yà ni a ti tọ́ kúrò; a sì tú wọn ká síwájú àti ṣẹ́hìn lórí erékùṣù òkun; ibi tí wọ́n wà kò sí ẹnìkan nínú wa tí ó mọ̀, àfi pé a mọ̀ pé a ti tọ́ wọn kúrò. Láti ìgbà tí a sì ti tọ́ wọn kúrò, àwọn ohun wọ̀nyí ni a ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn, àti pẹ̀lú nípa gbogbo àwọn tí a ó tú ká tí a ó sì fọnka lẹ́hìn èyí, nítorí ti Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì; nítorí wọ́n ó sé ọkàn wọn le sí; nítorí-èyi, a ó tú wọn ká lãrín gbogbo àwọn orílẹ-èdè gbogbo ènìyàn yíò sì kórìra wọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, lẹ́hìn ti àwọn Kèfèrí yíò tọ́jú wọn, tí Olúwa sì ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí órí àwọn Kèfèrí ti ó sì ti gbé wọn sókè fún ọ̀págún, ti a sì ti gbé àwọn ọmọ wọn ní apá wọn, ti a sì ti gbé àwọn ọmọbìnrin wọn sí órí èjìká wọn, kíyèsĩ àwọn ohun wọ̀nyí nípa èyí tí a sọ̀ jẹ́ ti ayé yí; nítorí báyĩ ni awọn májẹ̀mú Olúwa pẹ̀lú àwọn bàbá wa; ó sì tọ́ka sí àwọn ọjọ́ tí ńbọ̀ fún wa, àti pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa gbogbo tí ó jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì. Ó s ì túmọ̀ s í pé àkókò nã mbọ̀wá lẹ́hìn tí a bá ti tú gbogbo ará ilé Isráẹ́lì ká tí a sì fọn wọn ka, tí Olúwa Ọlọ́run yíò gbé orílẹ̀-èdè alágbára sókè lãrín àwọn Kèfèrí, bẹ̃ni, àní lórí ojú ilẹ̀ yí; nípasẹ̀ wọn sì ni a o tú irú-ọmọ wa ká. Lẹ́hìn tí a bá sì ti tú irú-ọmọ wa ká, Olúwa Ọlọ́run yíò tẹ̀ síwájú láti ṣe iṣẹ́ ìyanu lãrín àwọn Kèfèrí, èyí tí yíò jẹ́ ti iye nlá sí irú-ọmọ wa; nítorí-èyi, a fi wé bíbọ wọn nípa ọwọ́ àwọn Kèfèrí àti gbígbé wọn ní apá wọn àti sórí èjìká wọn. Yíò s ì j ẹ́ ìtóye pẹ̀lú s í àwọn Kèfèrí; kì í sì í ṣe sí àwọn Kèfèrí nìkan ṣùgbọ́n sí gbogbo ará ilé Isráẹ́lì, sí mímú wá sí ìmọ̀ àwọn májẹ̀mú ti Bàbá ọ̀run sí Ábráhámù, tí ó wípé: Nínú irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo ìbátan ayé. Èmi sì fẹ́, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé kí ẹ̀yin mọ̀ pé a kò lè bùkún fún gbogbo ìbátan ayé bíkòṣepé òun bá fi apá rẹ̀ hàn ní ojú àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí-èyi, Olúwa Ọlọ́run yíò tẹ̀ síwájú láti fi apá rẹ̀ hàn ní ojú àwọn orílẹ̀-èdè, ní mímú awọn májẹ̀mú rẹ̀ àti ìhìn-rere rẹ̀ wá kãkiri sí àwọn tí ó jẹ́ ará ilé Isráẹ́lì. Nítorí-èyi, òun yíò tún mú wọn jáde wá láti ìgbèkun, a ó sì jùmọ̀ kó wọn jọ sí àwọn ilẹ̀ ìní wọn; a ó sì mú wọn jáde wá láti ìṣókùnkùn àti jáde láti òkùnkùn; wọn yíò sì mọ̀ pé Olúwa ni Olùgbàlà wọn àti Olùràpadà wọn, Ẹni Alágbára Isráẹ́lì. Èjẹ̀ ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì, èyí tí í ṣe àgbèrè gbogbo ayé, yíò sì yípadà sórí ara wọn; nítorí wọn yíò jagun lãrín àwọn tìkaláawọn, idà ti ọwọ́ ara wọn yíò sì wá sórí ara wọn, wọn yíò sì mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn ní àmupara. Orílẹ̀-ede gbogbo tí yíò dìde ogun sí ọ, A! ará ilé Isráẹ́lì, ni wọn yíò dojúkọ ara wọn, wọn yíò sì ṣubú sínú kòtò èyí tí wọ́n gbẹ́ láti dẹkùn mú àwọn ènìyàn Olúwa. Gbogbo àwọn tí ó bá sì dojú ìjà kọ Síónì ni a ó parun, àti àgbèrè nlá nì, ẹni tí ó ti yí àwọn ọ̀nà títọ́ ti Olúwa padà, bẹ̃ni, ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì, yíò ṣubú sí erùpẹ̀; títóbi sì ni ìṣubú rẹ̀ yíò jẹ́. Nítorí kíyèsĩ i, ni wòlĩ nã wí, àkókò nã mbọ̀wá kíákíá tí Sátánì kì yíò ní agbára mọ́ lórí ọkànàwọn ọmọ ènìyàn; nítorí ọjọ́ nã yíò dé láìpẹ́ tí gbogbo àwọn agbéraga àti àwọn tí ó nṣe búburú yíò dà bí àkékù koríko; ọjọ́ nã sì ńbọ̀wá tí a kò ní ṣe àìjó wọn. Nítorí àkókó yíò dé láìpẹ́ tí a ó tú ẹ̀kún ìbínú Ọlọ́run jáde sórí gbogbo àwọn ọmọ ènìyàn; nítorí òun kì yíò yọ̣́da kí ènìyàn búburú run olódodo. Nítorí-èyi, òun yíò pa olódodo mọ́ nípasẹ̀ agbára rẹ̀, àní bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀kún ìbínú rẹ̀ kò lè ṣe àìwá, olódodo ni a ó sì pa mọ́, àní sí ìparun àwọn ọ̀tá wọn nípasẹ̀ iná. Nítorí-èyi, kò yẹ kí olódodo bẹ̀rù; nítorí báyĩ ni wòlĩ nã wí, a ó gbá wọ́n là, àní bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ iná. Kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi, mo wí fún yín, pé àwọn ohun wọ̀nyí kò lè ṣe àìwá láìpẹ́; bẹ̃ni, àní, ẹ̀jẹ́, àti iná, àti ìkũkú ẽfín kò lè ṣe àìwá; o di dandan ki o wa si ori ilẹ ayé yi; ó sì nwá sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara bí ó bá jẹ́ pé àwọn yí sé ọkàn wọn le sí Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì. Nítorí kíyèsĩ i, olódodo kì yíò ṣègbé; nítorí àkókò nã dájúdájú kò lè ṣe àìdé tí a ó ké gbogbo àwọn ẹni tí ndojú ìjà kọ Síónì kúrò. Dájúdájú Olúwa yíò sì pèsè ọ̀nà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, sí mímú àwọn ọ̀rọ̀ Mósè ṣẹ, èyí tí ó sọ, wípé: Wòlĩ kan ni Olúwa Ọlọ́run yín gbé sókè sí yín, bí èmi; òun ni kí ẹ̀yin kí ó má gbọ́ ní ohun gbogbo tí yíò má sọ fún yín. Yíò sì ṣe pé gbogbo àwọn ẹni tí kò bá gbọ́ wòlĩ nã ni a ó ké kúrò nínú àwọn ènìyàn. Àti nísisìyí èmi, Nífáì, sì sọ fún yín, pé wòlĩ yí nípa ẹni tí Mósè sọ̀rọ̀ jẹ́ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì; nítorí-èyi, òun yíò ṣe ìdájọ́ ní òdodo. Kò si yẹ kí olódodo bẹ̀rù, nítorí àwọn ni ẹnití a kò ní parun. Ṣùgbọ́n ìjọba ti èṣù ni, èyí tí a ó kọ́ sókè lãrín àwọn ọmọ ènìyàn, ìjọba èyí tí a fi kalẹ̀ lãrín wọn tí ó wà nínú ẹran ara— Nítorí àkókò nã yíò dé kánkán tí àwọn ìjọ onígbàgbọ́ gbogbo èyí tí a kọ́ sókè láti ní èrè, àti gbogbo àwọn wọnnì tí a kọ́ sókè láti gba agbára lórí ẹran ara, àti àwọn wọnnì tí a kọ́ sókè láti ni ókìkí ní ojú ayé, àti àwọn wọnnì tí nwá ìfẹ́kúfẹ̃ ti ẹran ara àti àwọn ohun ayé kiri, àti láti ṣe irú àìṣedẽdé gbogbo; bẹ̃ni, ní àkópọ̀, gbogbo àwọn wọnnì tí nṣe ti ìjọba èṣù ni àwọn tí ó yẹ kí ó bẹ̀rù, kí wọ́n sì wàrìrì, kí wọ́n sì gbọ̀n; àwọn ni àwọn wọnnì tí a kò lè ṣe àìmú rẹlẹ̀ nínú ekuru; àwọn ni àwọn wọnnì tí a kò lè ṣe àìrun bí àkékù koríko; èyí sì jẹ́ gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ wòlĩ. Àkókò nã nbọ̀wá kánkán tí a kò lè ṣe àìtọ́ olódodo sókè bí àwọn ẹgbọrọ màlũ inú agbo, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì kò sì lè ṣe àìjọba ní ìjọba, àti agbára, àti ipá, àti ògo nlá. Ó sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ jọ láti igun mẹ́rẹ̀rin ayé; ó sì kaye àgùtàn rẹ̀, wọ́n sì mọ̀ ọ́; yíò sì jẹ́ agbo kan àti olùṣọ́-àgùtàn kan; òun yíò sì bọ́ àwọn àgùtàn rẹ̀, nínú rẹ̀ ni wọn ó sì rí koríko. Àti nítorí ti òdodo àwọn ènìyàn rẹ̀, Sàtánì kò ní agbára; nítorí-èyi a kò lè tú u sílẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún púpọ̀; nítorí kò ní agbára lórí ọkàn àwọn ènìyàn,nítorí wọ́n wà ní òdodo, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì sì njọba. Àti nísisìyí kíyèsĩ, èmi, Nífáì, wí fún yín pé gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí kò lè ṣe àìwá gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara. Ṣugbọn, kíyèsĩ i, àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn gbogbo yíò gbé láìléwu nínú Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì bí ó bá ṣe pé wọ́n ronúpìwàdà. Àti nísisìyí èmi, Nífáì, sì ṣe é dé òpin; nítorí èmí kò tí gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ síwájú sí i nípa àwọn ohun wọ̀nyí. Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ̀yin rò ó wò pé àwọn ohun èyí tí a ti kọ si órí àwọn àwo idẹ jẹ́ òtítọ́; wọ́n sì jẹ́rĩ pé ènìyàn kò lè ṣàì ní ígbọ́ran sí àwọn òfin Ọlọ́run. Nítorí-èyi, kò yẹ kí ẹ ṣèbí pé èmi àti bàbá mi ni ó jẹ́ àwa nìkan tí ó ti jẹ́rĩ, tí ó sì kọ́ wọn pẹ̀lú. Nítorí-èyi, bí ẹ̀yin bá ní ígbọ́ran sí àwọn òfin, tí ẹ sì forítì í dé òpin, a ó gbà yín là ní ọjọ́ ìkẹhìn. Báyĩ ni ó sì rí. Àmín. 1 Léhì sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ òmìnira—Irú-ọmọ rẹ̀ ni a ó túká ti a ó sì pa bí wọ́n bá kọ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì sílẹ̀—Ó gba àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ níyànjú láti gbé ìhámọ́ra òdodo wọ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa. ÀTI nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí èmi, Nífáì, ti fi òpin sí kíkọ́ àwọn arákùnrin mi, bàbá wa, Léhì, sọ àwọn ohun púpọ̀ sí wọn pẹ̀lú, ó sì tún sọ fún wọn, àwọn ohun nlá èyí tí Olúwa ti ṣe fún wọn nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù. Ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn òtẹ̀ wọn lórí àwọn omi, àti àwọn ãnú Ọlọ́run ní dídá ẹ̀mí wọn sí, tí a kò gbé wọn mì nínú òkun. Ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú nípa ilẹ̀ ìlérí, èyí tí wọ́n ti gbà—bí Olúwa ti ní ãnú ní kíkìlọ̀ fún wa kí á lè sá jáde ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù. Nítorí, kíyèsĩ i, ni ó wí, èmi ti rí ìran kan, nínú èyí tí mo mọ̀ wípé a pa Jerúsálẹ́mù run; ìbá sì ṣepé àwa dúró ní Jerúsálẹ́mù àwa ìbá ti parun pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n, ni ó wí, l’áìṣírò awọn ìpọ́njú wa, àwa ti gba ilẹ̀ ìlérí, ilẹ̀ èyí tí ó jẹ́ àṣàyàn lórí gbogbo àwọn ilẹ̀ míràn; ilẹ̀ èyí tí Olúwa Ọlọ́run ti fi dá májẹ̀mú pẹ̀lú mi kí ó lè jẹ́ ilẹ̀ fún ìní irú-ọmọ mi. Bẹ̃ni, Olúwa ti fi ilẹ̀ yí dá májẹ̀mú sí mi, àti sí àwọn ọmọ mi títí láé, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn wọnnì tí a ó tọ́ jáde ní àwọn ilẹ̀ ìbí míràn nípa ọwọ́ Olúwa. Nítorí-èyi, èmi, Léhì, sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ Ẹ̀mí èyítí ó wà nínú mi, pé kò sí ẹnìkan tí yíò wá sínú ilẹ̀ yí àfi tí a ó bá mú wọn wá nípa ọwọ́ Olúwa. Nítorí-èyi, ilẹ̀ yí ni a yà sí mímọ́ sí ẹni tí oun yíò mú wá. Bí ó bá sì jẹ́ pé wọn yíò sìn ín gẹ́gẹ́bí àwọn òfin èyí tí ó ti fi fún wọn, yíò jẹ́ ilẹ̀ òmìnira sí wọn; nítorí-èyi, a kì yíò mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá láé sínú ìgbèkun; bí ó bá rí bẹ̃, yíò jẹ́ nítorí ti àìṣedẽdé; nítorí bí àìṣedẽdé bá di púpọ̀ a ó fi ilẹ̀ nã bú nítorí wọn, ṣùgbọ́n sí olódodo alábùkún fùn ni yíò jẹ́ títí láé. Sì kíyèsĩ i, ó jẹ́ ọgbọ́n pé kí á pa ilẹ̀ yí mọ́ síbẹ̀ kúrò ní ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè míràn; nítorí kíyèsĩ í, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ni yíò kún ilẹ̀ nã, tí kì yíò sí ibi fún ìní. Nítorí-èyi, èmi, Léhì, ti rí ìlérí kan gbà, pé níwọ̀n bí àwọn wọnnì tí Olúwa Ọlọ́run yíò mú jáde wá láti ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù bá pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, wọn yíò ṣe rere lórí ojú ilẹ̀ yí; a ó sì pa wọ́n mọ́ kúrò ní ìmọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè míràn, kí wọ́n lè gba ilẹ̀ yí fún àwọn tìkalãwọn. Bí ó bá sì ṣe pé wọn yíò pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ a ó bùkún wọn lórí ojú ilẹ̀ yí, kì yíò sì sí ẹnìkan láti yọ wọ́n lẹ́nu, tàbí láti mú ilẹ̀ ìní wọn kúrò; wọn yíò sì gbé láìléwu títí láé. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, nígbàtí àkókò nã bá dé tí wọn bá rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́, lẹ́hìn tí wọ́n bá ti gba àwọn ìbùkún nlá báyĩ láti ọwọ́ Olúwa—tí wọ́n ní ìmọ̀ nípa ẹ̀dá ayé, àti gbogbo ènìyàn, tí wọ́n mọ́ àwọn iṣẹ́ nlá Olúwa tí ó sì ya ni lẹ́nu láti ìgbà ẹ̀dá ayé; tí a fún wọn ní agbára láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́; tí wọ́n ní gbogbo òfin láti àtètèkọ́ṣe, tí a sì ti mú wọn wá nípasẹ̀ ọ́re rẹ̀ tí kò lópin sínú ojúlówó ilẹ̀ ìlérí yí—kíyèsĩ i, ni mo wí, bí ọjọ́ nã bá dé tí wọn yíò kọ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì sílẹ̀, Messia òtítọ́ nã, Olùràpadà wọn àti Ọlọ́run wọn, kíyèsĩ i, ìdájọ́ ẹni nã tí ó tọ́ yíò simi lórí wọn. Bẹ̃ni, òun yíò mú àwọn orílẹ̀-èdè míràn wá sọ́dọ̀ wọn, òun yíò sì fi agbára fún wọn, òun yíò sì gbà kúrò lọ́wọ́ wọn àwọn ilẹ̀ ìní wọn, òun yíò sì mú kí á tú wọn ká kí á sì pa wọ́n. Bẹ̃ni, bí ìran kan ti nkọjá sí òmíràn ìta-ẹ̀jẹ̀-sílẹ̀ yíò wà, àti ìbẹ̀wò nlá lãrín wọn; nítorí-èyi, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí; bẹ̃ni, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi. A! ẹ̀yin ìbá jí; ẹ jí kúrò ní ọ́run àsùnwọra, bẹ̃ni, àní kúrò ní ọ́run ọ̀run àpãdì, kí ẹ sì gbọn àwọn ẹ̀wọ̀n búburú èyí tí a fi dì yín kúrò, èyí tí ó jẹ́ àwọn ẹ̀wọ̀n tí ó di àwọn ọmọ ènìyàn, tí a fi gbé wọn ní ìgbèkun sọ̀kalẹ̀ sí ọ̀gbun ayérayé òṣì àti ìbànújẹ́. Ẹ jí! ẹ sì dìde kúrò nínú erùpẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ òbí tí nwárìrì, ara ẹni tí ẹ kò lè sài gbe sin laipẹ sinu ìsà-òkú tútù tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́, láti ibi tí àrìnrìn-àjò kan kò lè padà; ọjọ́ díẹ̀ sii èmi yíò sì lọ ọ̀nà gbogbo ayé. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, Olúwa ti ra ọkàn mi padà kúrò ní ọ̀run àpãdì; èmi ti kíyèsĩ ògo rẹ̀, a sì yí mi ká nínú apá ìfẹ́ rẹ̀ títí ayérayé. Mo sì fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí láti kíyèsĩ àwọn ìlànà àti àwọnìdájọ́ Olúwa; kíyèsĩ i, èyí ti jẹ́ àníyàn ọkàn mi láti ìpilẹ̀sẹ̀. Ọkàn mi ni a ti rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ìrora-ọkàn láti ìgbà dé ìgbà, nítorí mo ti bẹ̀rù, kí ó má bã jẹ́ pé nítorí ti líle ọkàn yín Olúwa Ọlọ́run yín yíò jáde wá ní ẹ̀kún ìbínú rẹ̀ sórí yín, kí á lè gé yín kúrò kí á sì pa yín run títí láé; Tàbí, kí ègún kí ó wá sórí yín fún ìwọ̀n àkókò ìran púpọ̀; àti tí a bẹ̀ yín wò nípasẹ̀ idà, àti nípasẹ̀ ìyàn, àti tí a kórìra yín, àti tí a tọ́ yín nípa ìfẹ́ àti ìgbèkun ti èṣù. A! ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, kí àwọn ohun wọ̀nyí má lè wá sórí yín, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè jẹ́ àṣàyàn àti àyànfẹ́ ènìyàn Olúwa. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ìfẹ́ rẹ̀ ni kí ó ṣẹ; nítorí àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ òdodo títí láé. Ó sì ti wí pé: Níwọ̀n bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́ ẹ̀yin yíò ṣe rere ní ilẹ̀ nã; ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin kò bá pa àwọn òfin mi mọ́ a ó gé yín kúrò níwájú mi. Àti nísisìyí kí ọkàn mi lè ní ayọ̀ nínú yín, àti kí ọkàn mi lè fi ayé yí sílẹ̀ pẹ̀lú inúdídùn nítorí yín, kí a má lè mú mi sọ̀kalẹ̀ wa pẹ̀lú ìbànújẹ́ àti írora-ọkàn lọ sí ìsà-òkú, ẹ dìde kúrò nínú erùpẹ̀, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, kí ẹ sì jẹ́ ọkùnrin, kí ẹ sì pinnu ní inú kan àti ní ọkàn kan, ní ìdàpọ̀ nínú ohun gbogbo, kí ẹ̀yin má bà sọ̀kalẹ̀ wá sínú ìgbèkun; Kí a má bà fi yín bú pẹ̀lú ègún kíkan; àti pẹ̀lú, kí ẹ̀yin má bà jigbèsè ìbínú Ọlọ́run ẹnití ó tọ́, sórí yín, sí ìparun, bẹ̃ni, ìparun ayérayé ti ọkàn àti ara. Ẹ jí, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi; ẹ gbé ìhámọ́ra òdodo wọ̀. Ẹ gbọn àwọn ẹ̀wọ̀n èyí tí a fi dì yín nù, kí ẹ sì jáde wá kúrò láti inú ìṣókùnkùn, kí ẹ sì dìde kúrò nínú erùpẹ̀. Ẹ máṣe ṣe ọ̀tẹ̀ mọ́ s í arákùnrin yín, ẹni tí ìrí rẹ̀ ti ni ógo, ẹni tí ó sì ti pa àwọn òfin mọ́ láti ìgbà tí a ti kúrò ní Jerúsálẹ́mù; ẹni tí ó sì ti jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, ní mímú wa jáde wá sí ilẹ̀ ìlérí; nítorí bí kò bá jẹ́ fún òun, àwa ìbá ti parun pẹ̀lú ebi nínú ijù; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ẹ̀yin nwá láti gba ẹ̀mí rẹ̀; bẹ̃ni, òun sì ti ní ìrora-ọkàn púpọ̀ nítorí yín. Mo sì bẹ̀rù mo sì wárìrì lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí yín, kí ó má bà tún jìyà; nítorí kíyèsĩ, ẹ̀yin ti fi ẹ̀sùn kán an pé ó nwá agbára àti àṣẹ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé òun kò wá agbára tàbí àṣẹ lórí yín, ṣùgbọ́n òun ti wá ògo Ọlọ́run, àti àlãfíà ayérayé tiyín. Ẹ̀yin sì ti kùn sínú nítorí òun ti ṣe kedere sí yín. Ẹ̀yin sọ wípé òun ti lo ìkannú; ẹ̀yin sọ wípé òun ti bínú sí yín; ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ìkannú rẹ̀ jẹ́ ìkannú tí agbára ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ó wà nínú rẹ̀; èyí tí ẹ sì pè ní ìbínú jẹ́ òtítọ́, gẹ́gẹ́bí èyí tí ó wà nínú Ọlọ́run, èyí tí kò lè dá lẹ́kun, tí ó nfihàn tìgboyà-tìgboyà nípa ti àwọn àìṣedẽdé yín. Ó sì di dandan kí agbára Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, àní sí pípa àṣẹ fún yín pe ẹ̀yin gbọdọ̀ gbọ́ran. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, kì í ṣe òun, ṣùgbọ́n Ẹ̀mi Olúwa èyí tí ó wà nínú rẹ̀ ni, èyí tí ó la ẹnu rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ sísọ tí kò lè pa á dé. Àti nísisìyí ìwọ ọmọkùnrin mi, Lámánì, àti pẹ̀lú Lẹ́múẹ́lì àti Sãmú, àti pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin mi tí wọ́n jẹ́ àwọn ọmọkùnrinÍṣmáẹ́lì, kíyèsĩ i, bí ẹ̀yin bá fetísílẹ̀ sí ohùn Nífáì ẹ̀yin kò ní parun. Bí ẹ̀yin bá sì fetísílẹ̀ sí i èmi fi ìbùkún kan sílẹ̀ fún yín, bẹ̃ni, àní ìbùkún mi èkíní. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá ní fetísílẹ̀ sí i èmi yíò mú ìbùkún mi èkíní kúrò, bẹ̃ni, àní ìbùkùn mi, yíò sì simi lórí rẹ̀. Àti nísisìyí, Sórámù, mo wí fún ọ: Kíyèsĩ i, ìwọ jẹ́ ìránṣẹ́ Lábánì; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a ti mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, èmi sì mọ̀ wípé ìwọ jẹ́ ọ̀rẹ́ òtítọ́ sí ọmọkùnrin mi, Nífáì, títí láé. Nítorí-èyi, nítorí tí ìwọ ti ṣe olóotọ́ irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún pẹ̀lú irú-ọmọ rẹ̀, tí wọn ó gbé ní alãfíà pẹ́ lórí ilẹ̀ yí; kò sì sí nkan, àfi tí yíò bá jẹ́ àìṣedẽdé lãrín wọn, tí yíò pa àlãfíà wọn lára tàbí dí i lọ́wọ́ lórí ojú ilẹ̀ yí títí láé. Nítorí-èyi, bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin Olúwa mọ́, Olúwa ti ya ilẹ̀ yí sí mímọ́ fún ãbò irú-ọmọ rẹ pẹ̀lú irú-ọmọ ti ọmọkùnrin mi. 2 Ìràpadà nwá nípasẹ̀ Messia Mímọ́—Òmìnira níti yíyàn (ìṣojúẹni) ṣe pàtàkì sí wíwà láyé àti ìlọ̀síwájú—Ádámù ṣubú kí àwọn ènìyàn lè wà—Àwọn ènìyàn ní òmìnira láti yan ìdásílẹ̀ àti ìyè àìnípẹ̀kun. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, Jákọ́bù, èmi wí fún ọ: Ìwọ jẹ́ àkọ́bí mi ní àwọn ọjọ́ wàhálà mi nínú ijù. Sì kíyèsĩ i, ní ìgbà èwe rẹ ìwọ ti ní ìpọ́njú àti ìrora-ọkàn púpọ̀, nítorí ti ìwàkúwà àwọn arákùnrin rẹ. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Jákọ́bù, àkọ́bí mi ní ijù, ìwọ mọ́ títóbi Ọlọ́run; òun yíò sì ya ípọ́njú rẹ sí mímọ́ fun èrè rẹ. Nítorí-èyi, ọkàn rẹ ni a ó bùkún fún, ìwọ yíò sì gbé láìléwu pẹ̀lú arákùnrin rẹ, Nífáì; àwọn ọjọ́ rẹ ni ìwọ yíò sì lò nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run rẹ. Nítorí-èyi èmi mọ̀ pé a ti rà ọ́ padà, nítorí ti òdodo Olùràpadà rẹ; nítorí ìwọ ti kíyèsĩ i pé ní kíkún àkókò ó mbọ̀wá láti mú ìgbàlà wá fún àwọn ènìyàn. Ìwọ sì ti kíyèsĩ i ní èwe rẹ, ògo rẹ̀; nítorí-èyi, a bùkún fun ọ àní gẹ́gẹ́bí àwọn ẹni tí òun yíò ṣe ìránṣẹ sí nínú ara; nítorí Ẹ̀mí nã jẹ́ ọ̀kannã, ní àná, ní òní, àti títí láé. A sì pèsè ọ̀nà kúrò nínú ìṣubú ènìyàn, ìgbàlà sì jẹ́ ọ̀fẹ́. Àwọn ènìyàn ni a sì kọ́ tó kí wọ́n mọ́ rere kúrò ní ibi. A sì fi òfin nã fún àwọn ènìyàn. Nípasẹ̀ òfin nã kò sì sí ẹran ara tí a dá láre; tàbí, nípasẹ̀ òfin nã ni a ké àwọn ènìyàn kúrò. Bẹ̃ni, nípasẹ̀ òfin ti ayé yí ni a fi ké wọn kúrò; àti pẹ̀lú, nípasẹ̀ òfin ti ẹ̀mí wọ́n parun kúrò nínú èyí tí ó jẹ́ rere, wọ́n sì di òtòṣì títí láé. Nítorí-èyi, ìràpadà mbọ̀wá nínú àti nípasẹ̀ Messia Mímọ́ nã; nítorí ó kún fún ọ́re-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́. Kíyèsĩ i, ó fi ara rẹ̀ silẹ bi ẹbọ fún ẹ̀sẹ̀, lati dahun àwọn ohun ti òfin bẽrè, fun gbogbo àwọn wọnnì tí ó ní ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́; kò sì sí àwọn míràn tí o lè dáhùn àwọn ohun ti òfin bẽrè. Nítorí-èyi, báwo ni pàtàkì látí sọ àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀ sí àwọn olùgbé ayé ṣe tóbi tó, kíwọ́n lè mọ̀ wípé kò sí ẹran ara tí ó lè gbé níwájú Ọlọ́run, àfi tí ó bá jẹ́ nípa àṣepé, àti ãnú, àti ore ọ̀fẹ́ ti Messia Mímọ́, ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara, tí ó sì tún gbà á nípa agbára Ẹ̀mí, kí ó le mú àjínde òkú wá ṣẹ, tí ó jẹ́ ẹni èkíní tí yíò jínde. Nítorí-èyi, òun jẹ́ èso àkọ́so fún Ọlọ́run, níwọ̀n bí òun yíò tí bẹ ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ ènìyàn; àwọn tí ó bá sì gbàgbọ nínú rẹ̀ ni a o gbàlà. Àti nítorí ti ẹ̀bẹ̀ fun olúkúlùkù, gbogbo ènìyàn wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run; nítorí-èyi, wọ́n dúró níwájú rẹ̀, kí á lè ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí òtítọ́ àti ìwà mímọ́ èyítí ó wà nínú rẹ̀. Nítorí-èyi, àwọn òpin òfin èyí tí Ẹní Mímọ́ nã ti fún ni, sí fífi ìyà èyí tí a ti fi lélẹ̀, ìyà èyí tí a fi lélẹ̀ tí ó wà ní àtakò sí ti àlãfíà èyí tí a fi lélẹ̀, láti dáhùn òpin ètùtù— Nítorí o di dandan, pé kí àtakò wà ní ohun gbogbo. Bí kò bá jẹ́ bẹ̃, àkọ́bí mi nínú ijù, a kò lè mú òdodo wá sí ṣíṣe, bẹ̃ni ìwà búburú, bẹ̃ni ìwà mímọ́ tàbí òṣì, bẹ̃ni rere tàbí búburú. Nítorí-èyi, ohun gbogbo di dandan ki wọ́n jẹ́ ìdàlù ní ọ̀kan; nítorí-èyi, bí yíò bá jẹ́ ara kan kò lè ṣe àìdúró bí ti òkú, tí kò ní ẹ̀mí bẹ̃ni ikú, tàbí ìdìbàjẹ́ tàbí àìdìbàjẹ́, àlãfíà tàbí òṣì, bẹ̃ni òye tàbí àìmọ̀. Nítorí-èyi, a níláti da a fún ohun asán; nítorí-èyi ìbá má sí ète ní òpin ẹ̀dá rẹ̀. Nítorí-èyi, ohun yí níláti pa ọgbọ́n Ọlọ́run àti àwọn ète ayérayé rẹ̀ run, àti pẹ̀lú agbára, àti ãnú, àti àìṣègbè Ọlọ́run. Bí ẹ̀yin bá sì wí pé kò sí òfin, ẹ̀yin yíò wí pẹ̀lú pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀. Bí ẹ̀yin bá wí pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin yíò wí pẹ̀lú pé kò sí òdodo. Bí kò bá sì sí òdodo kò sí inúdídùn. Bí kò bá sì sí òdodo tàbí inúdídùn kò sí ibáwí tàbí òṣì. Bí àwọn ohun wọ̀nyí kò bá sì wà kò sí Ọlọ́run. Bí Ọlọ́run kò bá sì wà àwa kò sí, bẹ̃ni ayé; nítorí ìbá má sí ẹ̀dá àwọn ohun, bẹ̃ni láti ṣe tàbí láti lè ṣe sí; nítorí-èyi, ohun gbogbo níláti di òfo. Àti nísisìyí, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, mo wí fún yín àwọn ohun wọ̀nyí fún èrè àti ẹ̀kọ́ yín; nítorí Ọlọ́run kan wà, ó sì ti dá ohun gbogbo, pẹ̀lú àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn, pẹ̀lú àwọn ohun láti ṣe àti àwọn ohun láti lè ṣe iṣẹ́ lé lórí. Láti sì mú ète ayérayé rẹ̀ ní òpin ènìyàn ṣẹ, lẹ́hìn tí ó ti dá àwọn òbí wa èkíní, àti àwọn ẹranko ìgbẹ́ àti àwọn ẹyẹ ojú sánmà, àti ní akotan, gbogbo ohun èyí tí a dá, ó di dandan kí àtakò wà; àní èso tí a kà lẽwọ̀ ní àtakò sí igi ìyè; tí ọ̀kan dùn tí èkejì sì korò. Nítorí-èyi, Olúwa Ọlọ́run fi fún ènìyàn kí ó lè ṣe ohunkóhun fúnrarẹ̀. Nítorí-èyi, ènìyàn kò lè ṣe fúnrarẹ̀ àfi tí ó bá jẹ́ pé a tàn án nípasẹ̀ ọ̀kan tàbí èkejì. Èmi, Léhì, gẹ́gẹ́bí àwọn ohun èyí tí mo ti kà, kò sì lè ṣe àì ṣèbí pé angẹ́lì Ọlọ́run kan, gẹ́gẹ́bí èyí tí a kọ, ti ṣubú láti ọ̀run wá; nítorí-èyi, ó di èṣù, nítorí tí ó ti wá ohun èyí tí ó burú níwájú Ọlọ́run. Nítorí tí ó sì ti ṣubú láti ọ̀run wá, tí ó sì ti di òtòṣì títí láé, ó wá òṣì gbogbo aráyé pẹ̀lú. Nítorí-èyi, ó wí fún Éfà, bẹ̃ni, àní ejò láéláé nì, ẹni tí ó jẹ́ èṣù, ẹni tíó jẹ́ bàbá gbogbo èké, nítorí-èyi ó wípé: Jẹ nínú èso tí a kà lẽwọ̀ nã, ìwọ kì yíò sì kú, ṣùgbọ́n ìwọ yíò dàbí Ọlọ́run, ní mímọ̀ rere àti búburú. Lẹ́hìn tí Ádámù àti Éfà sì ti jẹ nínú èso tí a kà lẽwọ̀ nã, a lé wọn jáde kúrò ní ọgbà Édẹ́nì, láti ro ilẹ̀. Wọ́n sì ti mú àwọn ọmọ jáde wá; bẹ̃ni, àní ìdílé gbogbo ayé. Àwọn ọjọ́ àwọn ọmọ ènìyàn ni a sì fà gùn, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí wọ́n lè ronúpìwàdà níwọ̀n ìgbà ti wọ́n bá wà nínú ẹran ara; nítorí-èyi, ipò wọn di ipò ìdánwò, a sì mú àkókò wọn pẹ́, gẹ́gẹ́bí àwọn òfin èyí tí Olúwa Ọlọ́run fi fún àwọn ọmọ ènìyàn. Nítorí ó fi òfin fún ni kí gbogbo ènìyàn lè ronúpìwàdà; nítorí tí ó fihàn sí gbogbo ènìyàn pé wọ́n ti sọnù, nítorí ìrékojá àwọn òbí wọn. Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, bí ó bá ṣe pé Ádámù kò ti rékọjá òun ìbá má ti ṣubú, ṣùgbọ́n òun ìbá ti wà nínú ọgbà Édẹ́nì. Gbogbo ohun èyí tí a dá ìbá sì tì wà ní ipò kannã nínú èyí tí wọ́n wà lẹ́hìn tí a dá wọn; wọn ìbá sì ti wà títí láé, tí wọn kò sì ní ní òpin. Wọn ìbá má sì ti ní àwọn ọmọ; nítorí-èyi wọn ìbá ti dúró ní ipò àìlẹ́ṣẹ̀, tí wọn kò ní ayọ̀, nítorí wọn kò mọ́ òṣì; tí wọn kò ṣe rere, nítorí wọn kò mọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ohun gbogbo ni a ti ṣe ní ọgbọ́n rẹ̀ ẹni tí ó mọ́ ohun gbogbo. Ádámù ṣubù kí àwọn ènìyàn lè wà; àwọn ènìyàn sì wà, kí wọ́n lè ní ayọ̀. Messia sì mbọ̀wá ní kíkún àkókò, kí ó lè ra àwọn ọmọ ènìyàn padà kúrò ní ìṣubú nì. Àti nítorí tí a sì ti rà wọ́n padà kúrò ní ìṣubú nì wọ́n ti di òmìnira títí láé, ní mímọ́ rere kúrò ní búburú; láti ṣe fúnrawọn kì í ṣe kí á sì mú wọn ṣe, àfi tí ó bá jẹ́ nípasẹ̀ ìjìyà òfin ní ọjọ́ nlá àti ti ìkẹhìn, gẹ́gẹ́bí àwọn òfin èyí tí Ọlọ́run ti fi fún ni. Nítorí-èyi, àwọn ènìyàn wà ní òmìnira nípa ti ara; ohun gbogbo ni a sì fi fún wọn tí ó jẹ́ yíyẹ fún ènìyàn. Wọ́n sì wà ní òmìnira láti yan ìdásílẹ̀ àti ìyè àìnípẹ̀kun, nípa Onílàjà nlá ti gbogbo ènìyàn, tàbí láti yan ìgbèkùn àti ikú, gẹ́gẹ́bí ìgbèkùn àti agbára ti èṣù; nítorí ó nwá kí gbogbo ènìyàn lè di òtòṣì bí ti ara rẹ̀. Àti nísisìyí, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó gbé ojú sókè sí Onílàjà nlá nã, kí ẹ sì fetísílẹ̀ sí àwọn òfin nlá rẹ̀; kí ẹ sì jẹ́ olóotọ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ, kí ẹ sì yan ìyè àìnípẹ̀kun, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀; Kí ẹ má sì ṣe yan ikú ayérayé, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ ti ara àti búburú èyí tí mbẹ nínú rẹ̀, èyí tí ó fún ẹ̀mí èṣù ní agbára láti dì nígbèkùn, láti mú yin sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀run àpãdì, pe kí ó lè jọba lórí yín ní ìjọba tirẹ̀. Èmi ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ wọ̀nyí sí gbogbo yín, ẹyin ọmọkùnrin mi, ní àwọn ọjọ́ ìdánwò mi ìkẹhìn; èmi sì ti yan ipa-ọ̀nà rere, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ wòlĩ nã. Èmi kò sì ní ohun míràn tí mo gbé ka iwájú bíkòṣe ti àlãfíà ọkàn yín títí ayé. Àmín. 3 Jósẹ́fù ní Égíptì rí àwọn ará Nífáì nínú ìran—Ó sọtẹ́lẹ̀ nípa Joseph Smith, aríran tí ọjọ́ ìkẹhìn; nípa Mósè, ẹni tí yíò gba Isráẹ́lì sílẹ̀; àti nípa jíjáde wá Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí mo wí fún ọ, Jósẹ́fù, àbígbẹ̀hìn mi. A bí ọ ní ijù àwọn ìpọ́njú mi; bẹ̃ni, ní àwọn ọjọ́ ìrora-ọkàn mi tí ó pọ̀ jùlọ ni ìyá rẹ bí ọ. Kí Olúwa sì ya ilẹ̀ yí sí mímọ́ fún ọ pẹ̀lú, èyí tí ó jẹ́ ilẹ̀ iyebíye jùlọ, fún ìní rẹ àti ìní irú-ọmọ rẹ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ, fún ãbo rẹ títí láé, bí ó bá ṣe pé ẹ̀yin yíò pa àwọn òfin Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì mọ́. Àti nísisìyí, Jósẹ́fù, àbígbẹ̀hìn mi, ẹni tí mo ti mú jáde kúrò ní ijù àwọn ìpọ́njú mi, kí Olúwa kí ó bùkún ọ títí láé, irú-ọmọ rẹ ni a kì yíò parun pátápátá. Nítorí kíyèsĩ i, ìwọ ni irúọmọ inú mi; èmi sì jẹ́ àtẹ̀lé Jósẹ́fù ẹni tí a gbé ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ Égíptì. Nlá sì ni àwọn májẹ̀mú Olúwa èyí tí ó ṣe sí Jósẹ́fù. Nítorí-èyi, Jósẹ́fù rí ọjọ́ wa nítọ́tọ́. Ó sì gba ìlérí Olúwa, pé lára irú-ọmọ inú rẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yíò gbé ẹ̀ká ódodo kan sókè sí ará ilé Isráẹ́lì; kì í ṣe Messia nã, ṣùgbọ́n ẹ̀ká éyí tí a ó ṣẹ́ kúrò, bíótilẹ̀ríbẹ̃, tí a ó rántí ni àwọn májẹ̀mú Olúwa pé a ó fi Messia nã hàn sí wọn ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, ní ẹ̀mí agbára, sí mímú wọn jáde kúrò ní òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀—bẹ̃ni, kúrò ní òkùnkùn tí ó pamọ́ àti kúrò ní ìgbèkùn sí òmìnira. Nítorí Jósẹ́fù jẹ́rĩ nítọ́tọ́, wípé: Aríran kan ni Olúwa Ọlọ́run mi yíò gbé sókè, ẹni tí yíò jẹ́ àṣàyàn aríran sí irú-ọmọ inú mi. Bẹ̃ni, Jósẹ́fù sọ nítọ́tọ́ pé: Báyĩ ní Olúwa wí fún mi: Àṣàyàn aríran kan ni èmi yíò gbé sókè lára irú-ọmọ inú rẹ; a ó sì gbé e níyì ga lãrín irú-ọmọ inú rẹ. Àti sí òun ni èmi yíò sì fi òfin fún pé òun yíò ṣe iṣẹ́ kan fún irú-ọmọ inú rẹ, àwọn arákùnrin rẹ̀, èyí tí yíò jẹ́ iye nlá sí wọn, àní sí mímú wọn wá sí ìmọ̀ àwọn májẹ̀mú èyí tí mo ti ṣe pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ. Èmi yíò sì fi òfin kan fún un pé òun kì yíò ṣe iṣẹ́ míràn, àfi iṣẹ́ èyí tí èmi yíò pàṣẹ fún un. Èmi yíò sì ṣe é ní títóbi ní ojú mi; nítorí òun yíò ṣe iṣẹ mi. Òun yíò sì jẹ́ ẹni nlá bí ti Mósè, ẹni tí mo ti sọ pé èmi yíò gbé sókè sí ọ, láti gba àwọn ènìyàn mi là, A! ará ilé Isráẹ́lì. Mósè sì ni èmi yíò gbé sókè, láti gba àwọn ènìyàn rẹ là kúrò ní ilẹ̀ Égíptì. Ṣùgbọ́n aríran kan ni èmi yíò gbé sókè láti irú-ọmọ inú rẹ; òun sì ni èmi yíò fi agbára fún láti mú ọ̀rọ̀ mi jáde wá fún irú-ọmọ rẹ—kò sì jẹ́ sí mímú ọ̀rọ̀ mi jáde wá nìkan, ni Olúwa wí, ṣùgbọ́n sí fífi òye ọ̀rọ̀ mi yé wọn, èyí tí yíò ti jáde lọ ṣíwajú lãrín wọn. Nítorí-èyi, irú-ọmọ inú rẹ yíò kọ̀wé; irú-ọmọ inú Júdà nã yíò sì kọ̀wé; àti èyí tí a ó sì kọ nípa ọwọ́ irú-ọmọ inú rẹ, àti pẹ̀lú èyí tí a ó kọ nípa ọwọ́ irúọmọ Júdà, yíò jùmọ̀ dàgbà, sí dídãmú àwọn ayédèrú ẹ̀kọ́ àtítítú ìjà ká, àti fífi àlãfíà lalẹ̀ lãrín irú-ọmọ inú rẹ, àti mímú wọn wá sí ìmọ̀ àwọn baba wọn ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, àti pẹ̀lú sí ìmọ̀ májẹ̀mú mi, ni Olúwa wí. Àti nínú àìlera ni a ó sì sọ ọ́ di alágbára, ní ọjọ́ nã ti iṣẹ́ mi yíò bẹ̀rẹ̀ lãrín gbogbo àwọn ènìyàn mi, sí mímú ọ padà sípò, A! ará ilé Isráẹ́lì, ni Olúwa wí. Báyĩ sì ni Jósẹ́fù sọtẹ́lẹ̀, wípé: Kíyèsĩ, aríran nì ni Olúwa yíò bùkún fun; àwọn tí ó bá sì nwá láti pa á run ni a ó parun; nítorí ìlérí yí, èyí tí mo ti gbà lọ́wọ́ Olúwa, níti irú-ọmọ inú mi, ni a ó mú ṣẹ. Kíyèsĩ, mímú ìlérí yí ṣẹ dá mi lójú; Orúkọ mi ni a ó sì fi pè é; yíò sì jẹ̃ tẹ̀lé orúkọ bàbá rẹ̀. Òun yíò sì rí bí èmi; fún ohun nã, èyí tí Olúwa yíò mú jáde wá nípa ọwọ́ rẹ̀, nípasẹ̀ agbára Olúwa yíò mú àwọn ènìyàn mi wá sí ìgbàlà. Bẹ̃ni, báyĩ ni Jósẹ́fù sọtẹ́lẹ̀: Mo ni idánilójú nípa nkan yí, àní bí mo ṣe ni idánilójú ìlérí ti Mósè; nítorí Olúwa ti wí fún mi, èmi yíò pa irú-ọmọ rẹ mọ́ títí láé. Olúwa sì ti wípé: Èmi yíò gbé Mósè kan dìde; èmi yíò sì fi agbára fún un nínú ọ̀pá kan; èmi yíò sì fi ìdájọ́ fún un ní ìkọ̀wé. Síbẹ̀ èmi kì yíò tú ahọ́n rẹ̀ sílẹ̀, tí yíò sọ̀rọ̀ púpọ̀, nítorí èmi kì yíò ṣe é ní alágbára ní sísọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n èmi yíò kọ òfin mi fún un, nípa ìka ọwọ́ tèmi; èmi yíò sì pèsè agbọ̀rọ̀sọ kan fún un. Olúwa sì wí fún mí pẹ̀lú pé: èmi yíò gbé dìde sí irú-ọmọ inú rẹ; èmi yíò sì pèsè agbọ̀rọ̀sọ kan fun un. Èmi, kíyèsĩ i, èmi yíò sì fi fún un wipe oun yíò kọ ìwé irú-ọmọ inú rẹ, sí irú-ọmọ inú rẹ; agbọ̀rọ̀sọ irú-ọmọ inú rẹ nã yíò sì kéde rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí òun yíò sì kọ yíò jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí ó jẹ́ yíyẹ ní òye mi kí ó jáde lọ sí irú-ọmọ inú rẹ. Yíò sì dàbí ẹnipé irú-ọmọ inú rẹ ti kígbe sí wọn láti inú erùpẹ̀ wá; nítorí mo mọ́ ìgbàgbọ́ wọn. Wọn yíò sì kígbe láti inú erùpẹ̀ wá; bẹ̃ni, àní ìrònúpìwàdà sí àwọn arákùnrin wọn, àní lẹ́hìn tí ìrandíran púpọ̀ ti lọ nípasẹ̀ wọn. Yíò sì ṣe tí igbe wọn yíò lọ, àní gẹ́gẹ́bí ìdẹ̀rùn àwọn ọ̀rọ̀ wọn. Nítorí ìgbàgbọ́ wọn àwọn ọ̀rọ̀ wọn yíò jáde láti ẹnu mi wá sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ inú rẹ; àìlágbára àwọn ọ̀rọ̀ wọn sì ni èmi yíò mú lágbára nínú ìgbàgbọ́ wọn, sí rírántí májẹ̀mú mi èyí tí mo ṣe pẹ̀lú àwọn bàbá yín. Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, ọmọ mi Jósẹ́fù, gẹgẹ báyĩ ni bàbá mi ti ìgbà àtijọ́ sọtẹ́lẹ̀. Nítorí-èyi, nítorí ti májẹ̀mú yí, ìwọ jẹ́ alábùkún fún; nítorí a kì yíò pa irú-ọmọ rẹ run, nítorí wọn yíò fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ ìwé nã. Alágbára kan ni a ó sì gbé dìde lãrín wọn, ẹni tí yíò ṣe rere púpọ̀, àti ní ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe, tí yíò jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí ó tayọ, láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó lágbára, àti láti ṣe ohun nì èyí tí ó jẹ́ títóbi ní ojú Ọlọ́run, sí mímú láti ṣe ìmúpadà sípò sí ará ilé Isráẹ́lì, àti sí irúọmọ àwọn arákùnrin rẹ. Àti nísisìyí, alábùkún fún ni ìwọ, Jósẹ́fù. Kíyèsĩ i, ìwọ kéré; nítorí-èyi fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀arákùnrin rẹ, Nífáì, a ó sì ṣe é sí ọ àní gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo ti sọ. Rántí àwọn ọ̀rọ̀ bàbá rẹ tí o nkú lọ. Àmín. 4 Léhì gba ìran àtẹ̀lé rẹ̀ níyànjú ó sì súre fún wọn—Ó kú a sì sin ín—Nífáì nṣògo nínú ọ́re Ọlọ́run—Nífáì fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sínú Olúwa títí láé. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, èmi, Nífáì, sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ nípa èyí tí bàbá mi ti sọ̀, nípa ti Jósẹ́fù, ẹni tí a gbé lọ sí ilẹ̀ Égíptì. Nítorí kíyèsĩ i, ó sọtẹ́lẹ̀ nítọ́tọ́ nípa ti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀. Àwọn ìsotẹ́lẹ̀ èyí tí ó sì kọ, kò sí púpọ̀ tí ó tóbijù. Ó sì sọtẹ́lẹ̀ nípa wa, àti àwọn ìran wa ìgbà tí mbọ̀; a sì kọ wọ́n sórí àwọn àwo idẹ. Nítorí-èyi, lẹ́hìn tí bàbá mi ti fi òpin sí ọ̀rọ̀ sísọ nípa ti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ ti Jósẹ́fù, ó pe àwọn ọmọ Lámánì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, ó sì wí fún wọn: Kíyèsĩ i, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, àti ẹ̀yin ọmọbìnrin mi, tí ó jẹ́ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin àkọ́bí mi, èmi nfẹ́ wípé kí ẹ fi etí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi. Nítorí Olúwa Ọlọ́run ti wípé: Níwọ̀n bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́ ẹ̀yin yíò ṣe rere ní ilẹ̀ nã; níwọ̀n bí ẹ̀yin kò bá sì pa àwọn òfin mi mọ́ a ó gé yín kúrò níwájú mi. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ẹ̀yin ọmọkùnrinmi àti ẹ̀yin ọmọbìnrin mi, èmi kò lè sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibojì mi àfi tí èmi bá fi ìbùkún sílẹ̀ sórí yín; nítorí kíyèsĩ ì, èmi mọ̀ wípé bí a bá tọ́ yín dàgbà ní ọ̀nà tí ẹ̀yin yíò tọ ẹ̀yin kì yíò kúrò nínú rẹ̀. Nítorí-èyi, bí a bá fi yín gégun, kíyèsĩ i, èmi fi ìbùkún mi sílẹ̀ sórí yín, kí á lè mú ègun nã kúrò lórí yín kí á sì dáhùn rẹ̀ lórí àwọn òbí yín. Nítorí-èyi, nítorí ti ìbùkún mi Olúwa Ọlọ́run kì yíò jẹ́ kí ẹ parun; nítorí-èyi, òun yíò ni-áanú sí yín àti sí irú-ọmọ yín títí láé. Ó sì ṣe tí lẹ́hìn tí bàbá mi ti fi òpin sí ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Lámánì, ó jẹ́ kí á mú àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Lẹ́múẹ́lì wá síwájú òun. Ó sì sọ fún wọn, wípé: Kíyèsĩ i, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi àti ẹ̀yin ọmọbìnrin mi, tí ẹ jẹ́ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin ọmọkùnrin mi èkejì; kíyèsĩ i mo fi fún yín ìbùkún kannã èyí tí mo fi fún àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Lámánì; nítorí-èyi, a kì yíò pa yín run pátápátá; ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀hìn irú-ọmọ yín ni a ó bùkún fún. Ó sì ṣe tí nígbà tí bàbá mi ti fi òpin sí ọ̀rọ̀ sísọ sí wọn, kíyèsĩ i, ó sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì, bẹ̃ni, àti gbogbo agbolé rẹ̀ pãpã. Lẹ́hìn tí ó sì ti fi òpin sí ọ̀rọ̀ sísọ sí wọn, ó sọ̀rọ̀ sí Sãmú, wípé: alábunkun-fun ni ìwọ, àti irú-ọmọ rẹ; nítorí ìwọ yíò jogún ilẹ̀ nã bí ti arákùnrin rẹ Nífáì. A ó sì ka irú-ọmọ rẹ pẹ̀lú irú-ọmọ rẹ̀; ìwọ yíò sì dàbí ti arákùnrin rẹ pãpã, àti irú-ọmọ rẹ yíò dàbí ti irú-ọmọ rẹ̀; a ó sì bùkún-fún ọ ní gbogbo àwọn ọ́jọ́ rẹ. Ó sì ṣe lẹ̀hìn tí bàbá mi, Léhì, ti bá gbogbo agbolé rẹ̀ sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ ọkàn rẹ̀ àti Ẹ̀mí Olúwa èyí tí mbẹ nínú rẹ̀, ó darúgbó. Ó sì ṣe tí ó kú, tí a sì sin ín. Ó sì ṣe tí láìpé ojọ́ púpọ̀ lẹ́hìn ikú rẹ̀, Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì àtí àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì bínú sí mi nítorí ti àwọn ìbáwi Olúwa. Nítorí èmi, Nífáì, ni a rọ̀ láti sọ̀rọ̀ sí wọn, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀; nítorí mo ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun sí wọn, àti bàbá mi pẹ̀lú, kí ó tó kú; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sísọ èyí tí a kọ sórí àwọn àwo mi míràn; nítorí apákan tí ó jẹ́ ìwé ìtàn jùlọ ni a kọ sórí àwọn àwo mi míràn. Si órí àwọn wọ̀nyí sì ni mo kọ àwọn ohun ọkàn mi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé-mímọ́ èyí tí a fín sórí àwọn àwo idẹ. Nítorí ọkàn mi yọ̀ nínú ìwé-mímọ́, ọkàn mi sì rò wọ́n, ó sì kọ wọ́n fún ẹ̀kọ́ àti ànfàní àwọn ọmọ mi. Kíyèsĩ i, ọkan mi yọ̀ nínú àwọn ohun Olúwa; ọkàn mi sì nrò títí lọ lórí àwọn ohun èyí tí mo ti rí tí mo sì ti gbọ́. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, l’áìṣírò ti ọ́re nlá Olúwa, ní fífi àwọn iṣẹ́ nlá àti ti ìyanu rẹ̀ hàn mí, ọkàn mi kígbe sókè: A! Èmi ọkùnrin òṣì! Bẹ̃ni, ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́ nítorí ti ẹran ara mi; ẹ̀mí mi kẹ́dùn nítorí ti àìṣedẽdé mi. A yí mi ká kiri, nítorí àwọn ìdánwò àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó fi ìrọ̀rùn rọ̀gbàká mi. Nígbàtí mo bá sì fẹ́ láti yọ̀, ọkàn mi nkérora nítorí ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi; bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo mọ́ ẹní tí mo ti gbẹ́kẹ̀lé. Ọlọ́run mi ti jẹ́ alatilẹhin mi; ó ti tọ́ mi já àwọn ìpọ́njú mi nínú ijù; ó sì ti pa mí mọ́ lórí àwọn omi ibú nlá wọnnì. Ó ti fi ìfẹ́ rẹ̀ kún mi, àní sí jíjẹ ẹran ara mi run. Ó ti dãmú àwọn ọ̀tá mi, sí mímú wọn láti gbọ̀n níwájú mi. Kíyèsĩ i, ó ti gbọ́ igbe mi nígbà ọ̀sán, ó sì ti fi ìmọ̀ fún mi nípa ìran ní ìgbà-òru. Nígbà ọ̀sán sì ni mo gbóyà si ní àdúrà tí ó lágbára níwájú rẹ̀; bẹ̃ni, ohùn mi ni mo ti rán lọ sí òkè; àwọn angẹ́lì sì sọ̀kalẹ̀ wá wọ́n sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún mi. Lórí àwọn ìyẹ́ apá Ẹ̀mí rẹ̀ sì ni a ti gbé ara mi lọ sórí àwọn òkè gíga-gíga. Ojú mi sì ti kíyèsĩ àwọn ohun nlá, bẹ̃ni, àní tí o tóbi jù fún ènìyàn; nítorí-èyi a fi àṣẹ fúnmi ki èmi máṣe kọ wọ́n. Njẹ́, bí èmi bá ti rí àwọn ohun nlá báyĩ, bí Olúwa ní ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn bá ti bẹ àwọn ènìyàn wò ní ãnú púpọ̀ báyĩ, ẽṣe tí ọkàn mi yíò fi sọkún tí ẹ̀mí mi yíò sì fi lọ́ra ní àfonífojì ìrora-ọkàn, tí ẹran ara mi yíò sì ṣòfò kúrò, tí agbára mí yíò sì fi fàsẹ́hìn, nítorí ti àwọn ìpọ́njú mi? Èéṣe tí èmi yíò sì fi yọ̣́da sí ẹ̀ṣẹ̀, nítorí ẹran ara mi? Bẹ̃ni, ẹ̃ṣe tí èmi yíò fi ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ìdánwò, tí ẹni búburú nì yíò ní ãyè ní ọkàn mi láti pa àlãfíà mi run kí ò sì pọ́n ẹ̀mí mi lójú? Èéṣe tí èmi fi nbínú nítorí ọ̀tá mi? Jí, ọkàn mi! Máṣe soríkọ́ ní ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Yọ̀, A! ọkàn mi, kí o másì ṣe fi ãyè fún ọ̀tá ọkàn mi mọ́. Máṣe tún bínú nítorí àwọn ọ̀tá mi. Máṣe fa agbára mi sẹ́hìn nítorí àwọn ìpọ́njú mi. Yọ̀, A! ọkàn mi, sì kígbe sí Olúwa, sì wípé: A! Olúwa, èmi yíò yìn ọ́ títí láé; bẹ̃ni, ọkàn miyíò yọ̀ nínú rẹ, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi. A! Olúwa, ìwọ yíò ha ra ẹ̀mí mi padà bí? Ìwọ yíò ha gbà mí sílẹ̀ kúrò ní ọwọ àwọn ọ̀tá mi bí? Ìwọ yíò ha mú mi kí èmi lè gbọ̀n ní ìfarahàn ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí àwọn ilẹ̀kùn ọ̀run àpãdì máa tì títí níwájú mi, nítorí tí ọkàn mi ti ní ìrora ẹ̀mí mi sì ti ní ìròbìnújẹ́! A! Olúwa, ìwọ kì yíò ha tí ilẹkùn òdodo rẹ níwájú mi bí, kí èmi lè rìn ní ipa-ọ̀nà ti àfonífojì tí kò ga, kí èmi lè mú ògírí ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú! A! Olúwa, ìwọ yíò ha rọ̀gbà yí mi ká ní ẹ̀wù òdodo rẹ bí! A! Olúwa, ìwọ yíò ha ṣe ọ̀nà fun ìsálà mi níwájú àwọn ọ̀tá mi bí! Ìwọ yíò ha mú ipa-ọ̀nà mi tọ́ níwájú mi bí! Ìwọ kì yíò ha fi ohun ìdigbòlù sí ọ̀nà mi bí—ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó gbá ọ̀nà mi mọ́ níwájú mi, kí o másì ṣe so ọgbà yí ọ̀nà mi ká, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ọ̀tá mi. A! Olúwa, èmi ti gbẹ́kẹ̀lé ọ, èmi yíò sì gbẹ́kẹ̀lé ọ títí láé. Èmi kì yíò fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sí apá ẹran ara; nítorí mo mọ̀ wípé ègbé ni fún ẹni tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sí apá ẹran ara. Bẹ̃ni, ègbé ni fún ẹni tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sí ènìyàn tàbí tí ó fi ẹran ara ṣe agbára rẹ̀. Bẹ̃ni, mo mọ̀ wípé Ọlọ́run yíò fi fún ẹni tí ó bá bẽrè ní ọlọ̀lọpọ̀. Bẹ̃ni, Ọlọ́run mi yíò fi fún mi, bí èmi kò bá ṣì bèrè; nítorí-èyi èmi yíò gbé ohùn mi sókè sí ọ; bẹ̃ni, èmi yíò kígbe sí ọ, Ọlọ́run mi, àpáta òdodo mi. Kíyèsĩ i, ohùn mi yíò gòkè sí ọ títí láé, àpáta mi àti Ọlọ́run àìnípẹ̀kun mi. Àmín. 5 Àwọn ará Nífáì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ará Lámánì, wọ́n pa òfin Mósè mọ́, wọ́n sì kọ́ tẹ́mpílì kan—Nítorí ti àìgbàgbọ́ wọn, a ké àwọn ará Lámánì kúrò níwájú Olúwa, a fi wọ́n bú, wọ́n sì di pàṣán sí àwọn ará Nífáì. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 559 kí á tó bí Olúwa wa. Kíyèsĩ i, ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, kígbe púpọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run mi, nítorí ti ìbínú àwọn arákùnrin mi. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ìbínú wọn pọ̀síi sí mi, tóbẹ̃ tí wọ́n wá láti mú ẹ̀mí mi lọ. Bẹ̃ni, wọ́n nkùn sí mi, wípé: Arákùnrin àbúrò wa nrò láti jọba lórí wa; a sì ti ní ìdánwò púpọ̀ nítorí rẹ̀; nítorí-èyi, nísisìyí ẹ jẹ́kí á pa á, kí àwa má lè rí ìpọ́njú mọ́ nítorí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí kíyèsĩ i, àwa kì yíò gbà fun láti jẹ́ alákọ́so wa; nítorí ó jẹ́ ti àwa, tí a jẹ́ arákùnrin àgbà, láti jọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Nísisìyí èmi kò kọ sórí àwọn àwo wọ̀nyí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí wọ́n fi kùn sí mi. Sùgbọ́n ó tó mi láti sọ, pé wọ́n nwá láti mú ẹ̀mí mi kúrò. Ó sì ṣe tí Olúwa kìlọ̀ fún mi, wípé kí èmi, Nífáì, kí nlọ kúrò lọ́dọ̀ wọn kí nsì sá lọ sínú ijù, àti gbogbo àwọn tí yíò lọ pẹ̀lú mi. Nítorí-èyi, ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, mú ìdílé mi, àti pẹ̀lú Sórámù àti ìdílé rẹ̀, àti Sãmú, ẹ̀gbọ́n mi àti ìdíle rẹ̀, àti Jákọ́bù àti Jósẹ́fù, àwọn àbúrò mi, àti àwọn arábìnrin mi pẹ̀lú, àti gbogbo àwọn tí yíò lọ pẹ̀lú mi. Gbogbo àwọn tí yíò sì lọ pẹ̀lú mi ni àwọnwọnnì tí wọ́n gbàgbọ́ nínú àwọn ìkìlọ̀ àti àwọn ìfihàn Ọlọ́run; nítorí-èyi, wọ́n fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi. A sì kó àwọn àgọ́ wa àti àwọn ohun èyíkéyi tí ó bá lè ṣe fún wa, a sì rin ìrìn-àjò ní ijù fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀. Lẹ́hìn tí a sì ti rin ìrìn-àjò fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀ a tẹ́ àwọn àgọ́ wa dó. Àwọn ènìyàn mi sì fẹ́ pé kí á pe orúkọ ibẹ̀ ní Nífáì; nítorí-èyi, a pè e ní Nífáì. Gbogbo àwọn wọnnì tí ó wà pẹ̀lú mi sì mu lórí wọn láti pe ara wọn ní àwọn ènìyàn Nífáì. A sì gbìyànjú láti pa àwọn ìdájọ́, àti àwọn ìlànà, àti àwọn òfin Olúwa mọ́ nínú óhun gbogbo, gẹgẹbi òfin Mósè. Olúwa sì wà pẹ̀lú wa; a sì ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ; nítorí a fún irúgbìn kalẹ̀, a sì tún kórè ní ọ̀pọ̀. A sì bẹ̀rẹ̀sì tọ́jú ọ̀wọ́ ẹran, àti agbo ẹran, àti àwọn ẹran onirũru gbogbo. Èmi, Nífáì, sì ti mú àwọn ìwé ìrántí nì èyí tí a fín sórí àwọn àwo idẹ wá pẹ̀lú; àti bọ̣́lù nì pẹ̀lú, tàbí atọ́nà, èyítí a pèsè fún bàbá mi nípa ọwọ́ Olúwa, gẹ́gẹ́bí èyítí a kọ. Ó sì ṣe tí a bẹ̀rẹ̀sí ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀, tí a sì ndi púpọ̀ ní ilẹ̀ nã. Èmi, Nífáì, sì mú idà Lábánì, ní àwòṣe rẹ̀ mo sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ idà, kí àwọn ènìyàn tí à npè ní àwọn ará Lámánì báyĩ má bã wá bá wa kí wọ́n sì pa wá run ní ọ̀nàkọnà; nítorítí mo mọ́ ìríra wọn sí èmi àti àwọn ọmọ mi àti àwọn wọnnì tí a pè ní àwọn ènìyàn mi. Mo sì kọ́ àwọn ènìyàn mi láti kọ́ àwọn ilé, àti láti ṣiṣẹ́ ní irú igi gbogbo, àti níti irin, àti níti bàbà, àti níti idẹ, àti níti akọ-irin, àti níti wúrà, àti níti fàdákà, àti níti àwọn irin àìpò tútù oníyebíye, èyí tí ó wà ní ọ̀pọ̀ nlá. Èmi, Nífáì, sì kọ́ tẹ́mpìlì kan; mo sì kàn án bĩ irú tẹ́mpìlì ti Sólómọ́nì àfi pé a kò kọ́ ọ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun iyebíye; nítorí a kò lè rí wọn lórí ilẹ̀ nã, nítorí-èyi, a kò lè kọ́ ọ bí tẹ́mpìlì Sólómọ́nì. Ṣùgbọ́n irú kíkàn rẹ̀ jẹ́ bí ti tẹ́mpìlì ti Sólómọ́nì; iṣẹ́ èyí nã sì dára lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, mú kí àwọn ènìyàn mi lãpọn, kí wọ́n sì siṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ wọn. Ó sì ṣe tí wọ́n fẹ́ pé kí èmi jẹ́ ọba wọn. Ṣùgbọ́n èmi, Nífáì, nfẹ́ pé kí wọn má ní ọba; bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo ṣe fún wọn gẹ́gẹ́bí èyí tí ó wà ní ipá mi. Sì kíyèsĩ i, àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti mú ṣẹ sí àwọn arákùnrin mi, èyí tí ó sọ nípa wọn, pé kí èmi ó jẹ́ alákọ́so wọn àti olùkọ́ wọn. Nítorí-èyi, èmi ti jẹ́ alákọ́so wọn àti olùkọ́ wọn, gẹ́gẹ́bí àwọn òfin Olúwa, títí di àkókò tí wọ́n wá láti mú ẹ̀mi mi kúrò. Nítorí-èyi, ọ̀rọ̀ Olúwa ni a mú ṣẹ èyí tí ó wí fún mi, wípé: Níwọ̀n bí wọn kì yíò fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ a ó gé wọn kúrò níwájú Olúwa. Sì kíyèsĩ i, a gé wọn kúrò níwájú rẹ̀. Ó sì ti mú kí ìfibú wá sórí wọn, bẹ̃ni, àní ìfibú kíkan, nítorí ti àìṣedẽdé wọn. Nítorí kíyèsĩ i, wọ́n ti sé ọkàn wọn le síi, tí wọ́n ti di bí òkúta ìbọn; nítorí-èyi, bí wọ́n ṣe funfun, tí wọ́n sì lẹ́wà tí wọ́n sì ládùn lọ́pọ̀lọpọ̀, ki wọnmá bã jẹ́ ẹ̀tàn sí àwọn ènìyàn mi Olúwa Ọlọ́run mú kí àwọ̀ ara dúdú wá si órí wọn. Báyĩ í sì ni Olúwa Ọlọ́run wí: èmi yíò mú kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́gbin sí àwọn ènìyàn rẹ, àfi tí wọ́n bá ronúpìwàdà ní ti àìṣedẽdé wọn. A ó sì fi irú-ọmọ ẹni nã bú tí ó bá dàpọ̀ pẹ̀lú irú-ọmọ wọn; nítorí a ó fi wọ́n bú àní pẹ̀lú ìfibú kannã. Olúwa sì sọ ọ́, a sì ṣe é. Nítorí ti ìfibú wọn èyí tí ó wà l ó r í wọn wọ́n s ì di aláiníṣẹ́lápá ènìyàn, tí ó kún fún ìwà ìkà àti àrékérekè, wọ́n sì wá àwọn ẹranko ìgbẹ́ kiri nínú ijù. Olúwa Ọlọ́run sì wí fún mi: Wọn yíò jẹ́ pàṣán sí irú-ọmọ rẹ, láti rú wọn sókè ní ìrántí mi; níwọ̀n bí wọn kò bá ní rántí mi, kí wọ́n sì fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi, wọn yíò fi pàṣán ná wọ́n àní sí ìparun. Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, ya Jákọ́bù àti Jósẹ́fù sí mímọ́, kí wọn lè jẹ́ àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ lórí ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi. Ó sì ṣe tí a gbé ní irú ìgbé ayò. Ọgbọ̀n ọdún sì ti kọjá lọ láti ìgbà tí a ti kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Èmi, Nífáì, sì ti pa àwọn ìwé-ìrántí nì mọ́ sórí àwọn àwo mi, èyí tí mo ti ṣe, ti àwọn ènìyàn mi di báyĩ. Ó sì ṣe tí Olúwa Ọlọ́run wí fún mi: Ṣe àwọn àwo míràn; ìwọ yíò sì fín àwọn ohun púpọ̀ sórí wọn èyí tí ó dára lójú mi, fún èrè àwọn ènìyàn rẹ. Nítorí-èyi, èmi, Nífáì, láti ní ígbọ́ran sí àwọn òfin Olúwa, lọ mo sì ṣe àwọn àwo wọ̀nyí orí èyí tí mo ti fín àwọn ohun wọ̀nyí sí. Mo sì fín ohun èyí tí ó jẹ́ wíwù sí Ọlọ́run. Bí inú àwọn ènìyàn mi bá sì dùn sí àwọn ohun Ọlọ́run inú wọn yíò sì dùn sí àwọn ìfín mi èyí tí ó wà lórí àwọn àwo wọ̀nyí. Bí àwọn ènìyàn mi bá sì fẹ́ láti mọ́ apá tí ó pàtàkì jùlọ ní ti ìwé ìtàn àwọn ènìyàn mi wọn kò ní ṣe àìwádí àwọn àwo mi míràn. Ó sì tó mi láti sọ pé ogọ́jì ọdún ti kọjá lọ, a sì ti ní àwọn ogun àti àwọn ìjà ná pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa. 6 Jákọ́bù tún ìtàn àwọn Jũ sọ: Ìgbèkùn ti Bábílọ́nì àti àbọ̀dé; iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti ìyà ìkànmọ́ àgbélẽbú ti Ẹní Mímọ́ Ísráẹ́lì; ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n rí gbà lọ́wọ́ àwọn Kèfèrí; àti ìmúpadà sípò ọjọ́ ìkẹhìn ti àwọn Jũ nígbàtí wọ́n gbàgbọ́ nínú Messia. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àwọn ọ̀rọ̀ Jákọ́bù, arákùnrin Nífáì, èyí tí ó sọ sí àwọn ènìyàn Nífáì: Kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin àyànfẹ́ mi, èmi, Jákọ́bù, nítorítí Ọlọ́run ti pè mí, tí a sì yàn mí nípa ọ̀nà ètò mímọ́ rẹ̀, àti nítorítí a ti yà mí sí mímọ́ nípa ọwọ́ arákùnrin mi Nífáì, ẹni tí ẹ̀yin nwò bí ọba tàbí alãbò, àti ẹni tí ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé fún àìléwu, kíyèsĩ i ẹ̀yin mọ̀ pé èmi ti sọ àwọn ohun púpọ̀púpọ̀ fún yín. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo tún bã yín sọ̀rọ̀; nítorí mo nĩfẹ́ fún àlãfíà ọkàn yín. Bẹ̃ni, àníyàn mi pọ̀ fún yín; ẹ̀yin tìkarãyín sì mọ̀ pé ó ti wà nígbà-gbogbo. Nítorí mo tigbà yín níyànjú pẹ̀lú gbogbo ãpọn; mo sì ti kọ́ yín ní àwọn ọ̀rọ̀ bàbá mi; mo sì ti sọ̀rọ̀ sí yín nípa gbogbo àwọn ohun èyí tí a kọ, láti ẹ̀dá ayé. Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, èmi yíò sọ̀rọ̀ sí yin nípa àwọn ohun èyí tí mbẹ, àti èyí tí mbọ̀; nítoríèyi, èmi yíò ka àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah sí yín. Wọ́n sì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí arákùnrin mi ti fẹ́ kí èmi kí ó sọ fún yín. Mo sì sọ̀rọ̀ sí yín fún ànfàní tiyín, kí ẹ́yin kí ó lè kọ́ ẹ̀kọ́ kí ẹ sì yin orúkọ Ọlọ́run yín lógo. Àti nísisìyí, àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí èmi yíò kà jẹ́ àwọn èyí tí Isaiah sọ nípa gbogbo ará ilé Isráẹ́lì; nítorí-èyi, a lè fi wọ́n we yín, nítorí ẹyin jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì. Àwọn ohun púpọ̀ sì wà èyí tí a ti sọ nípasẹ̀ Isaiah èyí tí a lè fí wé yín, nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì. Àti nísisìyí, ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ nã: Báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsĩ i, èmi yíò gbe ọwọ́ mi sókè si àwọn Kèfèrí, èmi ó sì gbe ọ̀págún mi sókè sí àwọn ènìyàn; wọn yíò sì gbé àwọn ọmọkùnrin rẹ wá ní apá wọn, a ó sì gbé àwọn ọmọbìnrin rẹ ní èjìká wọn. Àwọn ọba yíò jẹ́ àwọn baba olutọ́jú rẹ, àti àwọn ayaba wọn yíò sì jẹ́ àwọn ìyá olutọ́jú rẹ; wọn yíò tẹríba fún ọ ní ìdojúbolẹ̀, wọn ó sì lá erùpẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ; ìwọ yíò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa; nítorí ojú kì yíò ti àwọn tí ó bá dúró dè mí. Àti nísisìyí èmi, Jákọ́bù, yíò sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Nítorí kíyèsĩ i, Olúwa ti fi hàn mí pé àwọn wọnnì tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, láti ibi tí àwa ti wá, ni a ti pa tí a sì gbé lọ ní ìgbèkùn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa ti fi hàn sí mi pé kí wọ́n tún padà. Ó sì ti fi hàn sí mi pẹ̀lú pé Olúwa Ọlọ́run, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, yíò fi ara rẹ̀ hàn sí wọn ní ẹran ara; lẹ́hìn tí òun yíò sì fi ara rẹ̀ hàn, wọn yíò nà á, wọn ó sì kàn án mọ́ àgbélèbú, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ angẹ́lì tí ó bámi sọ̀rọ̀. Lẹ́hìn tí wọ́n bá sì ti sé ọkàn wọn le tí wọn sì wa ọrùn wọn kì sí Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, kíyèsĩ i, ìdájọ́ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì nì yíò wá sórí wọn. Ọjọ́ nã sì mbọ̀wá tí a ó lù wọ́n tí a ó sì pọ́n wọn lójú. Nítorí-èyi, lẹ́hìn tí a bá darí wọn sí ìhín àti sí ọ̀hún, nítorí báyĩ ni angẹ́lì nã wí, púpọ̀ ni a ó pọ́n lójú ní ẹran ara, a kò sì ní jẹ́ kí wọ́n parun, nítorí ti àwọn àdúrà olódodo; a ó túwọn ká, a ó sì lù wọ́n, a ó sì kórìra wọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa yíò ni ãnú sí wọn, pé nígbàtí wọ́n yíò bá wá sí ìmọ̀ Olùràpadà wọn, a ó tún kó wọn jọ sí àwọn ilẹ̀ ìní wọn. Alábùkún-fún sì ni àwọn Kèfèrí, àwọn nípa ẹni tí wòlĩ nì ti kọ̀wé; nítorí kíyèsĩ i, bí ó bá rí báyĩ í pé wọn yíò ronúpìwàdà kí wọ́n má sì ṣe bá Síónì jà, kí wọn sì máṣe pa ara wọn pọ̀ mọ́ ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì, a ó gbà wọ́n là; nítorí Olúwa Ọlọ́run yíò mú àwọn májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ èyí tí ó ti ṣe sí àwọn ọmọ rẹ̀; fún ìdí èyí sì ni wòlĩ nì ti kọ àwọn ohun wọ̀nyí. Nítorí-èyi, àwọn tí ó bá bá Síónì àti àwọn ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa jà yíò lá erùpẹ̀ ẹsẹ̀ wọn; àwọn ènìyàn Olúwa kì yíò sì tijú. Nítorí àwọn ènìyàn Olúwa ni àwọn wọnnì tí ó dúró fún un; nítorí síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n dúró fún bíbọ̀ Messia náà. Sì kíyèsĩ i, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ wòlĩ nì, Messia nã yíò tún mú ara rẹ̀ ní ìgbà èkejì láti gbà wọ́n padà; nítorí-èyi, òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí wọn ní agbára àti ògo nlá, sí ìparun àwọn ọ̀tá wọn, nígbàtí ọjọ́ nã bá dé tí wọn yíò gbàgbọ́ nínú rẹ̀; òun kì yíò sì pa ẹnikẹ́ni run tí ó bá gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àwọn tí kò bá sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ ni a ó parun, àti nípasẹ̀ iná, àti nípasẹ̀ ẹ̀fũfùlíle, àti nípasẹ̀ ìsẹ̀lẹ̀, àti nípasẹ̀ ìta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti nípasẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn, àti nípasẹ̀ ìyàn. Wọn yíò sì mọ̀ pé Olúwa ni Ọlọ́run, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì. Nítorí a ha lè gba ìkógun lọ́wọ́ alágbára bí, tàbí àwọn ondè lọ́wọ́ àwọn ẹni tí ó tọ́ fún? Sùgbọ́n báyĩ ni Olúwa wí: A ó tilẹ̀ gba àwọn ondè kúrò lọ́wọ́ alágbára, a ó sì gba ìkógun lọ́wọ́ àwọn ẹni-ẹ̀rù; nítorí Ọlọ́run Alágbára yíò gba àwọn ènìyàn májẹ̀mú rẹ̀ là. Nítorí báyĩ ni Olúwa wí: Èmi yíò bá wọn jà tí ó bá bá yín jà— Èmi yíò sì bọ́ àwọn tí ó ni ọ́ lára, pẹ̀lú ẹran ara wọn; wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn ní àmuyó bí ọtí-wáínì dídùn; gbogbo ẹran ara yíò sì mọ̀ pé èmi Olúwa ni Olùgbàlà rẹ àti Olùràpadà rẹ, Ẹni Alágbára ti Jákọ́bù. 7 Isaiah sọ̀rọ̀ bí ti Messia—Messia nã yíò ní ahọ́n amòye—Òun yíò fi ẹ̀hìn rẹ̀ fún àwọn aluni—A kì yíò dãmú rẹ̀—Fi Isaiah 50 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Bẹ̃ni, nítorí báyĩ ni Olúwa wí: Èmi ti kọ̀ yín sílẹ̀ bí, tàbí èmi ti sọ yín nù kúrò títí láé bí? Nítorí báyĩ ni Olúwa wí: Níbo ni ìwé ìkọ̀sílẹ̀ ìyá yín gbé wà? Tani ẹni tí mo kọ̀ yín sílẹ̀ fún, tàbí tani nínú àwọn onígbèsè mi ni mo tà yín fún? Bẹ̃ni, tani ẹni tí mo tà yín fun? Kíyèsĩ i, nítorí àwọn àìṣe dẽdé yin ni ẹ̀yin ti ta ara yín, àti nítorí àwọn ìrékọjá yín ni a ṣe kọ ìyá yín sílẹ̀. Nítorí-èyi, nígbàtí mo dé, kò sí ẹnìkan; nígbàtí mo pè, bẹ̃ni, kò sí ẹnìkan láti dáhùn. A! ará ilé Isráẹ́lì, ọwọ́ mi ha kúrú tóbẹ̃ tí kò fi lè ràpadà bí, tàbí èmi kò ha ní agbára láti gba ni bí? Kíyèsĩ i ní ìbáwí mi mo gbẹ òkun, mo sọ odò nlá wọn di ijù àti ẹja wọn láti rùn nítorí tí àwọn omi nì ti gbẹ, wọ́n sì kú nítorí ti òùngbẹ. Mo fi ohun dúdú wọ àwọn ọ̀run, mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbora wọn. Olúwa Ọlọ́run ti fi ahọ́n amòye fún mi, kí èmi kí ó lè mọ̀ bí a ti í sọ̀rọ̀ ní àkókò sí yín, A! ará ilé Isráẹ́lì. Nígbàtí ẹ̀yin bá ni ãrẹ̀ ó njí yin ní òròwúrọ̀. Ó ṣí mi ní etí láti gbọ́ bí amòye. Olúwa Ọlọ́run ti ṣí mi ní etí, èmi kò sì ṣe àìgbọ́ràn, bẹ̃ni èmi kò yípadà. Mo fi ẹ̀hìn mi fún aluni nã, àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ntu irun. Èmi kò pa ojú mi mọ́ kúrò nínú ìtìjú àti ìtutọ́ sí. Nítorí Olúwa Ọlọ́run yíò ràn mí lọ́wọ́, nítorí-èyi èmi kì yíò dãmú. Nítorí-èyi ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta líle, èmi sì mọ̀ pé ojú kì yíò ti mí. Olúwa sì wà ní tòsí, ó sì dá mi láre. Tani yíò bá mi jà? Ẹ jẹ́ kí á dúró pọ̀. Tani í ṣe ẹlẹ́jọ́ mi? Jẹ́ kí ó súnmọ mi, èmi yíò sì lù ú pẹ̀lú agbára ẹnu mi. Nítorí Olúwa Ọlọ́run yíò ràn mí lọ́wọ́. Gbogbo àwọn tí yíò sì dá mi ní ẹ̀bi, kíyèsĩ i, gbogbo wọn yíò di ogbó bí ẹ̀wù, kòkòrò yíò sì jẹ wọ́n run. Tani nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa, tí ó gba ohùn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbọ́, tí nrìn nínú òkùnkùn tí kò sì ní ìmọ́lẹ̀? Kíyèsĩ i gbogbo èyín tí ó dá iná, tí ẹ fi ẹta iná yí ara yín ká, ẹ máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá. Èyí ni yíò jẹ́ ohun tí ó wá láti ọwọ́ mi—ẹ̀yin yíò dùbúlẹ̀ nínú ìrora-ọkàn. 8 Ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, Olúwa yíò tu Síónì nínú yíò sì kó Isráẹ́lì jọ—Àwọn tí a ràpadà yíò wá sí Síónì lãrín ayọ̀ nla—Fi Isaiah 51 àti 545 kí á tó bí Olúwa wa. Gbọ́ ti èmi, ẹ̀yin tí ntẹ̀lé òdodo. Wo àpáta nì nínú èyí tí a ti gbẹ́ yín, àti ihò kòtò nì láti ibi tí a gbé ti wà yín. Ẹ wo Ábráhámù, bàbá yín, àti Sárà, òun tí ó bí yín; nítorí òun nìkan ni mo pè, mo sì súre fún un. Nítorí Olúwa yíò tu Síónì nínú, òun yíò tu gbogbo ibi òfò rẹ̀ nínú; òun yíò sì ṣe aginjù rẹ̀ bí Édẹ́nì, àti asálẹ̀ rẹ̀ bí ọgbà Olúwa. Ayọ̀ àti inúdídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ìdúpẹ́ àti ohùn orin. Tẹ́tílélẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi, sì fi etí sí mi, A! orílẹ̀-èdè mi; nítorí òfin kan yíò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá, èmi yíò sì gbé ìdájọ́ mi kalẹ̀ fún ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn. Òdodo mi wà nítòsí; ìgbàlà mi ti jáde lọ, apá mi yíò sì ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. Àwọn erékùsù yíò dúró dè mí, apá mi ni wọn yíò sì gbẹ́kẹ̀lé. Ẹ gbé ojú yín sókè sí àwọn ọrun, kí ẹ sì wo ayé nísàlẹ̀; nítorí àwọn ọ̀run yíò fẹ́ lọ bí ẽfín, ayé yíò sì di ogbó bí ẹ̀wù; àwọn tí ngbé inú rẹ̀ yíò sì kú bákannã. Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yíò wà títí láé, òdodo mi kì yíò sì parẹ́. Gbọ́ ti èmi, ẹ́yin tí ó mọ́ òdodo, ènìyàn nínú àyà ẹnití mo ti kọ òfin mi sí, ẹ máṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn, ẹ má sì ṣe fòyà ẹ̀sín wọn. Nítorí kòkòrò yíò jẹ wọ́n bí ẹ̀wù, ìdin yíò sì jẹ wọ́n bí irun àgùtàn. Ṣùgbọ́n òdodo mi yíò wà títí lae, àti ìgbàlà mi láti ìran dé ìran. Jí, jí! Gbé agbára wọ̀, A! apá Olúwa; jí bí ní ọjọ́ ìgbanì. Ìwọ ha kọ́ ni ó gé Ráhábù, tí ó sì ṣá drágónì ní ọgbẹ́? Ìwọ ha kọ́ ni ó gbẹ òkun, omi ibú nlá wọnnì; tí ó ti sọ àwọn ibú òkun di ọ̀nà fún àwọn ìràpadà láti gbà kọjá? Nítorínã, àwọn ẹni-ìràpada Olúwa yíò padà, wọn ó sì wá pẹ̀lú orin kíkọ sí Síónì; ayọ̀ àìnípẹ̀kun àti ìwà mímọ́ yíò sì wà ní orí wọn; wọn yíò sì rí inúdídùn àti ayọ̀ gbà; ìrora-ọkàn àti ọ̀fọ̀ yíò fò lọ. Èmi ni òun; bẹ̃ni, èmi ni ẹni tí ntù yín nínú. Kíyèsĩ i, tani ìwọ, tí ìwọ fi bẹ̀rù ènìyàn, ẹni tíyíò kú, àti ti ọmọ ènìyàn, tí a ó ṣe bí koríko? Tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́da rẹ, tí ó ti na àwọn ọ̀run jádewá, tí ó sì ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ìwọ sì ti nbẹ̀rù nígbàgbogbo lójojúmọ́, nítorí ìrúnú aninilára nì, bí ẹnipé ó ti múra láti panirun? Níbo sì ni ìrúnú aninilára nã ha gbé wà? Òndè tí a ti ṣí nípò yára, ki a bá lè tú u sílẹ̀, àti kí ó má bà kú sínú ihò, tàbí kí oúnjẹ rẹ̀ má bà tán. Ṣùgbọ́n èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ìgbì rẹ̀ hó; Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ni orúkọ mi. Èmi sì ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ, mo sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀ ní òjìji ọwọ́ mi, kí èmi kí ó lè gbin àwọn ọ̀run kí èmi sì lè fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, àti kí èmi lè wí fún Síónì pé: Kíyèsĩ i, ìwọ ni ènìyàn mi. Jí, jí, dìde dúró, A! Jerúsálẹ́mù, tí ó ti mu ní ọwọ́ Olúwa ago ìrúnú rẹ̀—ìwọ ti mu gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ago tí ìwárìrì fọn jáde— Kò sì sí ẹnìkan láti tọ́ ọ nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó bí; bẹ̃ni tí ó fà á lọ́wọ́, nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí òun tọ́ dàgbà. Àwọn ọmọkùnrin méjì wọ̀nyí ni ó wá sọ́dọ̀ rẹ, tani yíò kãnú fún ọ—ìdáhóró àti ìparun rẹ, àti ìyàn àti idà—nípa tani èmi yíò sì tù ọ́ nínú? Àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin ti dákú, àfi àwọn méjì wọ̀nyí; wọ́n dùbúlẹ̀ ní gbogbo ìkóríta; bí ẹfọ̀n nínú àwọn, wọ́n kún fún ìrúnú Olúwa, ìbáwí Ọlọ́run rẹ. Nítorínã gbọ́ èyí ná, ìwọ ẹni tí a pọ́n lójú, tí ó sì mu àmuyó, tí kì í sì ṣe nípa ọtí-wáínì: Báyĩ ni Olúwa rẹ wí, Olúwa àti Ọlọ́run rẹ nṣìpẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀; kíyèsĩ i, èmi ti gba ago ìwárìrì kúrò lọ́wọ́ rẹ, gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ago ìrúnú mi; ìwọ kì yíò tún mu ú mọ́. Ṣùgbọ́n èmi ó fi í sí ọwọ́ àwọn tí ó pọ́n ọ lójú; tí wọ́n ti wí fún ọkàn rẹ pé: Wólẹ̀, kí a bá lè rékọjá—ìwọ sì ti tẹ́ ara rẹ sílẹ̀ bí ilẹ̀ àti bí ìta fún àwọn tí ó rékọjá. Jí, jí, gbé agbára rẹ wọ̀, A! Síónì; gbé aṣọ arẹwà rẹ wọ̀, A! Jerúsálẹ́mù, ìlú mímọ́ nã; nítorí láti ìgbà yí lọ aláìkọlà àti aláìmọ́ kì yíò wọ inú rẹ mọ́. Gbọn ekuru kúrò ní ara rẹ; dìde, jóko, A! Jerúsálẹ́mù; tú ara rẹ kúrò nínú ìdè ọrùn rẹ, A! òndè ọmọbìnrin Síónì. 9 A ó kó àwọn Jũ jọ ní gbogbo àwọn ilẹ̀ ìlérí wọn—Ètùtù nã nra ènìyàn padà kúrò ní Ìṣubú nì—Àwọn ara ti òkú yíò jáde wá láti isà òkú, àti àwọn ẹ̀mí wọn láti ọ̀run àpãdì àti láti ọ̀run rere—A ó dá wọn lẹ́jọ́—Ètùtù nì ngba ni là lọ́wọ́ ikú, ọ̀run àpãdì, èṣù, àti oró àìnípẹ̀kun—Olódodo ni a ó gbàlà ní ìjọba Ọlọ́run—Àwọn Ìjìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ni a gbé kalẹ̀—Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì ni olùpamọ́ ẹnu ọ̀nà òde. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi ayanfẹ, èmi ti ka àwọn ohun wọ̀nyí kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ nípa àwọn májẹ̀mú Olúwa tí ó tí dá pẹ̀lú gbogbo ará ilé Isráẹ́lì— Tí ó ti sọ sí àwọn Jũ, nípasẹ̀ ẹnu àwọn wòlĩ mímọ́ rẹ̀, àní láti ìbẹ̀rẹ̀ sísàlẹ̀, láti ìran dé ìran, títí àkókò nã yíò dé tí a ó mú wọn padà sí ìjọ onígbàgbọ́ òtítọ́ àti agbo Ọlọ́run; nígbàtí a ó kó wọn jọ sílẹ̀ sí àwọn ilẹ̀ ìní wọn, tí a ó sì fi wọ́n kalẹ̀ ní gbogbo àwọn ilẹ̀ ìlérí wọn. Kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo sọ àwọn ohun wọ̀nyí fún yín kí ẹ̀yin lè yọ̀, kí ẹ sì gbé orí yín sókè títí láé, nítorí ti àwọn ìbùkún tí Olúwa Ọlọ́run yíò fi fún àwọn ọmọ yín. Nítorí mo mọ̀ pé ẹ̀yin ti wádĩ púpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín, láti mọ̀ nípa àwọn ohun tí mbọ̀; nítorí-èyi mo mọ̀ pé ẹ̀yin mọ̀ pé ẹran ara wa kò lè ṣe àìsòfò kúrò kí ó sì kú; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nínú ara wa ni àwa yíò rí Ọlọ́run. Bẹ̃ni, èmi mọ̀ pé ẹ̀yin mọ̀ pé nínú ara ni òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn wọnnì ní Jerúsálẹ́mù, láti ibi tí àwa ti wá; nítorí ti ó yẹ kí ó wà lãrín wọn; nítorí ó yẹ kí Ẹlẹ́dã nlá kí ó yọ̣́da ara rẹ̀ láti di ẹni tí nsìn ènìyàn nínú ẹran ara, kí ó sì kú fún gbogbo ènìyàn, kí gbogbo ènìyàn lè di ẹni tí nsìn ìn. Nítorí bí ikú ti wá sí orí gbogbo ènìyàn, láti mú ìlànà tí ó ni ãnú ti Ẹlẹ́dã nlá ṣẹ, o di dandan kí agbára àjínde òkú wà, o si di dandan ki àjínde òkú wá fún ènìyàn nípa ìdí ìṣubú nì; ìṣubú nã sì wá nípa ìdí ìrékọjá; nítorí tí ènìyàn sì di ìṣubú a ké wọn kúrò níwájú Olúwa. Nítorí-èyi, ó di dandan kí ètùtù àìnípẹ̀kun wà—àfi tí ó bá jẹ́ ètùtù àìnípẹ̀kun ìdìbàjẹ́ yí kò lè mu àìdìbàjẹ́ wọ̀. Nítorí-èyi, ìdájọ́ ekíní èyí ti ó wá sórí ènìyàn níláti dúró fún ìgbà àìnípẹ̀kun. Bí ó bá sì rí bẹ̃, ẹran ara yí níláti di fífi fi lé lẹ̀ láti jẹ rà àti láti fọ́ sí wẹ́wẹ́ lọ sínú ilẹ̀, láti máṣe dìde mọ́. A! ọgbọ́n Ọlọ́run, àanú àti ọ́re-ọ̀fẹ́ rẹ̀! Nítorí kíyèsĩ i, bí ẹran ara kò bá dìde mọ́ àwọn ẹ̀mí wa kò lè ṣe àìdi ẹni tí nfi oribalẹ fun angẹ́lì nì tí ó ṣubú kúrò níwájú Ọlọ́run Ayérayé, tí ó sì di èṣù, láti máṣe dìde mọ́. Àwọn ẹ̀mí wa kò sì lè ṣe àìdi bí ti òun, a sì di àwọn èṣù, angẹ́lì sí èṣù, tí a ó tì jáde kúrò níwájú Ọlọ́run wa, àti tí a ó dúró pẹ̀lú bàbá èké, nínú òṣì, bí oun tìkárarẹ̀; bẹ̃ni, sí ẹ̀dá nì tí ó tan àwọn òbí wa èkíní jẹ, tí ó pa ara rẹ̀ dà tí ó fẹ́rẹ̀ dàbí angẹ́lì ìmọ́lẹ̀ kan, tí ó sì rú àwọn ọmọ ènìyàn sókè sí àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn ti ìpànìyàn àti irú àwọn iṣẹ́ òkùnkùn tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ gbogbo. A! báwo ni ọ́re Ọlọ́run wa ṣe tóbi tó, ẹnití ó pèsè ọ̀nà fún ìsálà wa kúrò ní ìdìmú èyà búburú yí; bẹ̃ni, ẹ̀yà nì, ikú àti ọ̀run àpãdì, èyítí mo pè ní ikú ti ara, àti ikú ti ẹ̀mí pẹ̀lú. Àti nítorí ti ọ̀nà ìdásílẹ̀ Ọlọ́run wa, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, ikú yí, nípa èyítí mo ti sọ, èyítí ó jẹ́ ti ara, yíò jọ̀wọ́ òkú rẹ̀; ikú èyí tí nṣe ìsà òkú. Ikú yí, nípa èyítí mo sì ti sọ, èyítí ó jẹ́ ikú ti ẹ̀mí, yíò jọ̀wọ́ òkú rẹ̀; ikú ti ẹ̀mí èyítí i ṣe ọ̀run àpãdì; nítorí-èyi, ikú àti ọ̀run àpãdì kò lè ṣe àì jọ̀wọ́ òkú wọn, ọ̀run àpãdì kò sì lè ṣe àì jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀mí ìgbèkùn rẹ, ìsà òkú kò sì lè ṣe àì jọ̀wọ́ àwọn araìgbèkùn rẹ̀, àwọn ara àti àwọn ẹ̀mí àwọn ènìyàn ni a ó sì mú padà sípò ọ̀kan sí èkejì; ó sì jẹ́ nípasẹ̀ agbára àjínde òkú ti Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì. A! báwo ni ìlànà Ọlọ́run wa ṣe tóbi tó! Nítorí ní ọ̀nà míràn, párádísè Ọlọ́run kò lè ṣe àì jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀mí olódodo, àti isà òkú jọ̀wọ́ ara olódodo; ẹ̀mí àti ara ni a sì tún mú padà sípò òun tìkararẹ̀, gbogbo ènìyàn sì di aláìdìbàjẹ̀, àti aláìkú, wọ́n sì jẹ́ ọkàn alãyè, tí ó ní ìmọ̀ pípé bí ti àwa nínú ẹran ara, àfi tí ó jẹ́ pé ìmọ̀ wa yíò pé. Nítorí-èyi, àwà yíò ní ìmọ̀ pípé ní ti gbogbo ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, àti ìwà àìmọ́ wa, àti ìhòhò wa; olódodo yíò sì ní ìmọ̀ pípé nípa ìgbádùn wọn, àti òdodo wọn, tí a wọ̀ láṣọ mímọ́, bẹ̃ni, àní pẹ̀lú ẹ̀wú òdodo. Yíò sì ṣe pé nígbàtí gbogbo ènìyàn yíò bá ti kọjá láti ikú kíni yí sí ìyè, níwọ̀n bí wọn ti di aláìkú, wọn gbọ́dọ̀ farahàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ ti Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì; nígbànã sì ni ìdájọ́ yíò dé, nígbànã sì ni a kò ní ṣe àì dá wọn lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdájọ́ mímọ́ ti Ọlọ́run. Àti dájúdájú, bí Olúwa ti mbẹ, nítorí Olúwa Ọlọ́run ti sọ ọ́, ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ ayéraye rẹ̀, èyí tí kò lè rékọjá, pé àwọn tí ó bá jẹ́ olódodo yíò jẹ́ olódodo síbẹ̀síbẹ̀, àwọn tí ó bá sì jẹ́ elẽrí yíò jẹ́ elẽrí síbẹ̀síbẹ̀; nítorí-èyi, àwọn tí ó jẹ́ elẽrí ni èṣù àti àwọn angẹ́lì rẹ̀; wọn yíò sì kúrò lọ sínú iná àìlópin; tí a pèsè fún wọn; ìdálóró wọn sì rí bí adágún iná àti imi ọjọ́, tí ọwọ́ iná rẹ̀ gòkè sókè títí láé àti láé ti kò sì ní òpin. A! títóbi àti àìṣègbè ni Ọlọ́run wa! Nítorí ó ṣe gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti jáde lọ láti ẹnu rẹ̀, òfin rẹ̀ ni a kò sì lè ṣe àìmú ṣẹ. Ṣùgbón, kíyèsĩ i, àwọn olódodo, àwọn ènìyàn mímọ́ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, àwọn tí wọ́n ti gbàgbọ́ nínú Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, àwọn tí wọ́n tí faradà àwọn ágbélẽbú ayé, tí wọ́n sì ṣãtá ìtìjú rẹ̀, wọn yíò jogún ìjọba Ọlọ́run, èyítí a pèsè sílẹ̀ fún wọn láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, ayọ̀ wọn yíò sì kún títí láé. A! títóbi ni ãnú Ọlọ́run wa, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì! Nítorí ó gba àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ là lọ́wọ́ èyà búburú nì èṣù, àti ikú, àti ọ̀run àpãdì, àti adágún iná nì àti imí ọjọ́, èyítí ó jẹ́ oró àìnípẹ̀kun. A! báwo ni títóbi mímọ́ Ọlọ́run wa! Nítorí ó mọ́ ohun gbogbo, kò sì sí ohunkóhun tí òun kò mọ̀. Òun sì mbọ̀wá sínú ayé kí ó lè gba gbogbo ènìyàn là bí àwọn bá fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ̀; nítorí kíyèsĩ i, òun jìyà àwọn ìrora gbogbo ènìyàn, bẹ̃ni, àwọn ìrora ẹ̀dá alãyè gbogbo, àti àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé, tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé Ádámù. Ó sì jìyà èyí kí àjínde òkú lè rékọjá lórí gbogbo ènìyán, kí gbogbo ènìyàn lè dúró níwájú rẹ̀ ní ọjọ nla àti ti ìdájọ́ nì. Ó sì pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn pé wọn kò lè ṣe àì ronúpìwàdà, kí a sì rì wọn bọmi ní orúkọ rẹ̀, kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ pípé nínú Ẹni Mímọ́ Isráẹ́lì, bíbẹ̃kọ́ a kò lè gbà wọ́n là ní ìjọba Ọlọ́run. Bí wọn kò bá sì ronúpìwàdà kí wọ́n sì gbàgbọ́ ní orúkọ rẹ̀, kí a sì rì wọn bọmi ní orúkọ rẹ̀, kí wọ́n sì forítì í dé òpin, wọn kò lè ṣe àìjẹ́ ẹni ègbé; nítorí Olúwa Ọlọ́run, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, ti sọ ọ́. Nítorí-èyi, ó ti fi òfin kan fún ni; níbití a kò bá sì ti fi òfin fún ni kò sí ìjìyà; níbití kò bá sì sí ìjìyà kò sí ìdálẹ́bi; níbití kò bá sì sí ìdálẹ́bi àwọn ãnú Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì ní ẹ̀tọ́ lórí wọn, nítori ti ètùtù nì; nítorí a gbà wọn sílẹ̀ nípasẹ̀ agbára rẹ̀. Nítorí ètùtù nnì tẹ́ àwọn ìbẽrè àìṣègbè rẹ̀ lọ́rùn lórí gbogbo àwọn wọnnì tí a kò fi òfin fún, kí á lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà búburú nì, ikú àti ọ̀run àpãdì, àti èṣù, àti adágún iná ni àti imí ọjọ́, èyítí ó jẹ́ oró àìnípẹ̀kun; a sì mú wọn padà sípò Ọ l ọ́ r u n n ì t í ó f ú n wọn ní ẽmí, èyítí nṣe Ẹni Mímọ́ Isráẹ́lì. Ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí a fi òfin nã fún, bẹ̃ni tí ó ní gbogbo ofin Ọlọ́run, bí àwa, tí ó sì ré wọn kọjá, tí ó sì fi àwọn ọjọ́ ìdánwò rẹ̀ ṣòfò, nítorí búburú ni ipò rẹ̀! A! ète àrékérekè ẹni búburú nì! A! asán, àti àìlera, àti ẹ̀gọ̀ àwọn ènìyàn! Nígbàtí wọ́n bá kọ́ ẹ̀kọ́ wọ́n rò pé àwọn gbọ́n, wọn kò sì ní fetísílẹ̀ sí ìmọ̀ràn Ọlọ́run, nítorí wọ́n pa á tì, wọ́n ṣèbí wọn mọ́ ní tìkarãwọn, nítorí-èyi, ọgbọ́n wọn jẹ́ ẹ̀gọ̀ kò sì ṣe wọ́n ní ànfàní. Wọn yíò sì parun. Ṣùgbọ́n láti kọ́ ẹ̀kọ́ dára bí wọ́n bá fetísílẹ̀ sí àwọn ìmọ̀ràn Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn ọlọ́rọ̀, tí wọ́n ní ọrọ̀ ní ti àwọn ohun ayé. Nítorí tí wọ́n ní ọrọ̀ wọn kẹ́gàn àwọn tálákà, wọ́n sì nṣe inúnibíni sí àwọn ọlọ́kàn tútù, ọkàn wọn sì wà lórí ìṣura wọn; nítorí-èyi, ìṣura wọn ni ọlọ́run wọn. Sì kíyèsĩ i, ìṣura wọn yíò parun pẹ̀lú wọn bakannã. Ègbé sì ni fún adití tí kì yíò gbọ́ran; nítorí wọn yíò parun. Ègbé ni fún afọ́jú tí kì yíò ríran; nítorí wọn yíò parun bakannã. Ègbé ni fún aláìkọlà ní ọkàn, nítorí ìmọ̀ àwọn àìṣedẽdé wọn yíò lù wọ́n ní ọjọ́ ìkẹhìn. Ègbé ni fún elékẽ, nítorí a ó sọ ọ́ sísàlẹ̀ sí ọ̀run àpãdì. Ègbé ni fún apànìyàn tí ó mọ̣́mọ̀ pani, nítorí òun yíò kú. Ègbé ni fún àwọn tí ó nhu ìwà àgbèrè, nítorí a ó sọ wọ́n sísàlẹ̀ sí ọ̀run àpãdì. Bẹ̃ni, ègbé ni fún àwọn wọnnì tí nsin àwọn òrìṣà, nítorí èṣù gbogbo àwọn èṣù nṣe inúdídùn sí wọn. Àti, ní àkópọ̀, ègbé ni fún gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n kú sínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn; nítorí wọn yíò padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, wọn yíò sì kíyèsĩ ojú rẹ̀, wọn a sì wà nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn. A! ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ rántí bíburú ní rírékọjá sí Ọlọ́run Mímọ́, àti pẹ̀lú bíburú ìtũbá sí ẹ̀tàn ẹni àrékérekè nì. Ẹ rántí, láti ronú nípa ti ara jẹ́ ikú, láti ronú nípa ti ẹ̀mí sì jẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun. A! ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ fi etí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi. Ẹ rántí títóbi Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì. Ẹ máṣe sọ pé mo ti sọ àwọn ohun líle sí yín; nítorí bí ẹ bá sọ ọ́, ẹ̀yin yíòkẹ́gàn sí òtítọ́; nítorí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ Ẹlẹ́dá yín. Èmi mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ le si gbogbo ìwà àìmọ́; ṣùgbọ́n àwọn olódodo kò bẹ̀rù wọn, nítorí wọ́n fẹ́ràn òtítọ́ wọn kò sì dãmú. A! nígbànã, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ wá sọ́dọ̀ Olúwa, Ẹní Mímọ́ nì. Ẹ rántí pé àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ òdodo. Kíyèsĩ i, ọ̀nà fún ènìyàn jẹ́ tọ́ró, ṣùgbọ́n ó lọ ní ipa ọ̀nà tàrà níwájú rẹ̀, olùpamọ́ ẹnu ọ̀nà nã sì ni Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, òun kò sì gba ìrànṣẹ́ kan sí iṣẹ́ níbẹ̀; kò sì sí ọ̀nà míràn àfi nípasẹ̀ ẹnu ọ̀nà òdè nã; nítorí a kò lè tàn án jẹ, nítorí Olúwa Ọlọ́run ni orúkọ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì kànkùn, ni òun yíò ṣi-sílẹ̀ fún; àti àwọn ọlọgbọ́n, àti àwọn amòye, àti àwọn tí ó ní ọrọ̀, tí wọ́n nfẹ̀ sókè nítorí ti ẹ̀kọ́ wọn, àti ọgbọ́n wọn, àti ọrọ̀ wọn—bẹ̃ni, àwọn ni ẹni tí òun kẹ́gàn; àfi tí wọn yíò bá sì sọ àwọn ohun wọ̀nyí nù kúrò, tí wọ́n sì ro ara wọn wò bí aṣiwèrè níwájú Ọlọ́run, tí wọ́n sì wá sílẹ̀ ní ìjìnlẹ̀ ìrẹ̀lẹ̀, òun kì yíò ṣi-sílẹ̀ fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ohun ti àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye ni a ó pamọ́ kuro lójú wọn títí láé—bẹ̃ní, àlãfíà nì èyí tí a pèsè fún àwọn ènìyàn mímọ́. A! ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ mi. Kíyèsĩ i, èmi bọ́ àwọn ẹ̀wù mi, mo sì gbọ̀n wọ́n níwájú yín; mo gbàdúrà Ọlọ́run ìgbàlà mi kí ó síjúwò mí pẹ̀lú ojú ìwádĩ fífín rẹ̀; nítorí-èyi, ẹ̀yin yíò mọ̀ ní ọjọ́ ìkẹhìn, nígbàtí a ó ṣe ìdájọ́ fún gbogbo ènìyàn ní ti àwọn iṣẹ́ wọn, pé Ọlọ́run Isráẹ́lì jẹ́rĩ pé mo gbọn àwọn àìṣedẽdé yín kúrò ní ọkàn mi, àti pé mo dúró pẹ̀lú dídán níwájú rẹ̀, mo sì bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀jẹ̀ yín. A! ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ yí kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín; ẹ gbọn àwọn ẹ̀wọ́n rẹ̀ kúrò tí yíò dè yín pinpin; ẹ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run nì tí ó jẹ́ àpáta ìgbàlà yín. Ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀ fún ọjọ́ ológo nì nígbàtí a ó pín àìṣègbè fún olódodo, àní ọjọ́ ìdájọ́, kí ẹ̀yin má bà á súnkì pẹ̀lú ìbẹ̀rù búburú; kí ẹ̀yin má bà á rántí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ búburú yín ní pípé, kí á sì fi agbára mú yín láti kígbe sókè: Mímọ́, mímọ́ ni àwọn ìdájọ́ rẹ, A! Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè—ṣùgbọ́n mo mọ́ ẹ̀bi mi; mo ré òfin rẹ kọjá, àwọn ìrékọjá mi sì jẹ́ tèmi; èṣù sì ti gbà mí, tí èmi jẹ́ ìkógun sí òṣí búburú rẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi, ó ha yẹ kí èmi kí ó jí yín sí òtítọ́ búburú àwọn ohun wọ̀nyí bí? Njẹ́ èmi yíò dá ọkàn yín lóró bí inú yín bá mọ́ bí? Njẹ́ èmi yíò ṣe kedere sí yín gẹ́gẹ́bí kedere ti òtítọ́ bí a bá sọ yín di òmìnira kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kíyèsĩ i, bí ẹ̀yin bá jẹ́ mímọ́ èmi yíò bá a yín sọ̀rọ̀ nípa ìwà mímọ́; ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò ti jẹ́ mímọ́, tí ẹ̀yin sì nwò mí bí olùkọ́, kò lè ṣe àìyẹ kí èmi kí ó kọ́ yín ní ìgbẹ̀hìn ẹ̀ṣẹ̀. Kíyèsĩ i, ọkàn mi kórìra ẹ̀ṣẹ̀, ọkàn mi sì yọ̀ ní òdodo; èmi yíò sì yin orúkọ mímọ́ Ọlọ́run mi. Ẹ wá, ẹ̀yin arákùnrin mi, gbogbo ẹni tí npòùngbẹ, ẹ wá sí ibi àwọn omi; àti ẹni tí kò ní owó, ẹ wá rà kí ẹ sì jẹ; bẹ̃ni, ẹ wá ra wáìnì àti wàrà láìsí owó àti láìsí iye. Nítorí-èyi, ẹ máṣe ná owó fún èyí nì tí kò ní ìtóye, tàbí ṣe lãlã fun èyí nì tí kò lè tẹ́ ni lọ́rùn. Ẹ fetísílẹ̀ lẹ́sọ̀lẹsọ̀ sí mi, kí ẹ sì rántí àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo ti sọ; kí ẹ sì wá sọ́dọ̀ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, kí ẹ si jẹun lórí èyí tí kò lè parun, tabi tí kò lè bàjẹ́, ẹ sì jẹ́ kí ọkàn yín yọ̀ sí sísanra. Kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yín; ẹ gbàdúrà sí i léraléra nígbà ọ̀sán, kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀ nígba òru. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín yọ̀. Sì kíyèsĩ bí májẹ̀mú Olúwa ti tóbi tó, àti bí ìrẹ̀lè rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn ti tóbi to; àti nítorí títóbi rẹ̀, àti ọ́re-ọ̀fẹ́ àti ãnú rẹ̀, ó ti ṣe ìlérí fún wa pé a kò ní pa irú-ọmọ wa run pátápátá, gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara, ṣùgbọ́n pé òun yíò pa wọ́n mọ́; ní ìrandíran ìgbà tí mbọ̀ wọn yíò sì di ẹ̀ká ólódodo ti ará ilé Isráẹ́lì. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi yíò bá a yín sọ̀rọ̀ si; ṣùgbọ́n ní ọ̀la èmi yíò sọ ìyókù àwọn ọ̀rọ̀ mi fún yín. Àmín. 10 Àwọn Jũ yíò kan Ọlọ́run wọn mọ́ àgbélẽbú—A ó tú wọn ká títí dìgbà tí wọn ó bẹ̀rẹ̀sí gbàgbọ́ nínú rẹ̀—Ilẹ̀ Amẹ́ríkà yíò jẹ́ ilẹ̀ òmìnira níbití kò sí ọba tí yíò ṣe àkóso—Ẹ ṣe ìlàjà ara yín sí Ọlọ́run kí ẹ sì jèrè ìgbàlà nípa ore ọ̀fẹ́ rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí èmi, Jákọ́bù, tún bá yín sọ̀rọ̀, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, nípa ẹ̀ká òdodo yí nipa èyítí mo ti sọ̀. Nítorí kíyèsĩ i, àwọn ìlérí èyítí àwa ti rí gbà jẹ́ àwọn ìlérí sí wa gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara; nítorí-èyi, bí a ti fi hàn sí mi pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ wa yíò parun ní ẹran ara nítorí ti àìgbàgbọ́, bíótilẹ̀ríbẹ̃, Ọlọ́run yíò ni ãnú sí ọ̀pọ̀lọpọ̀; àwọn ọmọ wa ni a ó sì mú padà sípò, kí wọ́n lè wá sí èyí nì tí yíò fún wọn ní ìmọ̀ òtítọ́ ti Olùràpadà wọn. Nítorí-èyi, bí mo ṣe wí fún yín, o di yíyẹ dandan pé Krístì—nítorí ní òru àná angẹ́lì nã wí fún mi pé èyí ni yíò jẹ́ orúkọ rẹ̀—yíò wá lãrín àwọn Jũ, lãrín àwọn wọnnì tí ó jẹ́ ẹ̀yà tí ó burú jùlọ ní ayé; àwọn yíò sì kàn án mọ́ àgbélẽbú—nítorí báyĩ ni ó tọ́ sí Ọlọ́run wa, kò sì sí orílẹ̀-èdè míràn ní ayé tí yíò kan Ọlọ́run wọn mọ́ àgbélẽbú. Nítorí bí a bá ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu alágbára lãrín àwọn orílẹ̀-èdè míràn wọn yíò ronúpìwàdà, wọn ó sì mọ̀ pé òun jẹ́ Ọlọ́run wọn. Ṣùgbọ́n n í t o r í t i àwọn oyè àlùfã àrékéreke àti àwọn àìṣedẽdé, àwọn ti Jerúsálẹ́mù yíò sé ọrùn wọn le sí i, pé kí á kàn án mọ́ àgbélẽbú. Nítorí-èyi, nítorí ti àwọn àìṣedẽdé wọn, ìparun, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, àti ìta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ yíò wá sórí wọn; àwọn tí a kì yíò sì parun ni a ó túká lãrín gbogbo àwọn orílẹ èdè. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nígbàtí ọjọ́ nã yíò dé tí wọn yíò gbàgbọ́ nínú mi, pé èmi ni Krístì, nígbànã ni èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn bàbá wọn pé a ó mú wọn padà sípò ní ẹran ara, lórí ilẹ̀ ayé, sí àwọn ilẹ̀ ìní wọn. Yíò sì ṣe tí a ó kó wọn jọ pọ̀ láti ìfúnká pípẹ́ wọn, láti àwọn erékùsù òkun, àti láti àwọn ìpín mẹ́rin ayé; àwọn orílẹ̀ èdè àwọn Kèfèrí yíò sì tóbi ní ojú mi, ni Ọlọ́run wí, ní gbígbé wọn jádewá sí àwọn ilẹ̀ ìní wọn. Bẹ̃ni, àwọn ọba àwọn Kèfèrí yíò jẹ́ bàbá olùtọ́jú sí wọn, àwọn ayaba wọn yíò sì di ìyá olùtọ́jú; nítorí-èyi àwọn ìlérí Olúwa tóbi sí àwọn Kèfèrí, nítorí òun ti sọ ọ́, tãni o sì lè jiyàn si? Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ilẹ̀ yí, ni Ọlọ́run wí, yíò jẹ́ ilẹ̀ ìní yín, àwọn Kèfèrí ni a ó sì bùkún-fún lórí ilẹ̀ nã. Ilẹ̀ yí yíò sì jẹ́ ilẹ̀ òmìnira sí àwọn Kèfèrí, kì yíò sì sí àwọn ọba lórí ilẹ̀ nã, tí yíò gbé sókè sí àwọn Kèfèrí. Ẹ̀mì yíò sì dábọ́bò ilẹ̀ yí láti dojúkọ gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè míràn. Ẹni tí ó bá sì bá Síónì jà yíò parun, ni Ọlọ́run wí. Nítorí ẹni tí ó gbé ọba kan sókè sí mi yíò parun, nítorí èmi, Olúwa, ọba ọ̀run, yíò jẹ́ ọba wọn, èmi yíò sì jẹ́ ìmọ́lè sí wọn títí láé, tí ó bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi. Nítorí-èyi, nítorí ìdí èyí, kí a lè mu àwọn májẹ̀mú mi ṣẹ èyí tí mo ti ba àwọn ọmọ ènìyàn dá, tí èmi yíò ṣe sí wọn níwọ̀n bí wọ́n ṣe wà nínú ẹran ara, èmi kò lè ṣe àìpá àwọn iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ ti òkùnkùn, àti ti ìpànìyàn, àti ti ẹ̀gbin run. Nítorí-èyi, ẹni tí ó bá bá Síónì ja, àti Jũ àti Kèfèrí, àti tí ó wà ní ìdè àti ní òmìnira, àti ọkùnrin àti obìnrin, yíò parun; nítorí àwọn ni àwọn tí nṣe àgbèrè obìnrin ayé gbogbo; nítorí àwọn tí kò bá wà fún mi nlòdì sí mi, ni Ọlọ́run wa wí. Nítorí èmi yíò mú àwọn ìlérí mi ṣẹ èyí tí mo ti ba àwọn ọmọ ènìyàn dá, tí èmi yíò ṣe sí wọn níwọ̀n bí wọ́n ṣe wà nínú ẹran ara— Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, báyĩ ni Ọlọ́run wa wí: Èmi yíò pọ́n irú ọmọ yín lójú nípa ọwọ́ àwọn Kèfèrí; bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi yíò mú ọkàn àwọn Kèfèrí rọ̀, tí àwọn yíò jẹ́ bí bàbá sí wọn; nítorí-èyi, àwọn Kèfèrí ni a ó bùkún-fún tí a ó sì kà mọ́ ará ilé Isráẹ́lì. Nítorí-èyi, èmi yíò ya ilẹ̀ yí sí mímọ́ fún irú ọmọ yín, àti àwọn tí a ó kà mọ́ irú ọmọ yín, títí láé, fun ilẹ̀ ìní wọn; nítorí ó jẹ́ àṣàyàn ilẹ̀, ni Ọlọ́run wí fún mi, ga ju gbogbo àwọn ilẹ̀ míràn lọ, nítorí-èyi èmi yíò mú gbogbo ènìyàn tí ngbé lórí ilẹ̀nã ki wọn ó sìn mí, ni Ọlọ́run wí. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, njẹ́ bí ó ti ṣe pé Ọlọ́run wa aláanú ti fi irú ìmọ̀ nlá fún wa nípa àwọn ohun wọ̀nyí, ẹ jẹ́kí á rántí rẹ̀, kí á sì pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tì sí ápákan, kí á má sì ṣe sọ orí wa kodò, nítorí a kò gé wa kúrò; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a ti lé wa jáde kúrò ní ilẹ̀ ìní wa; ṣùgbọ́n a ti tọ́ wa lọ sí ilẹ̀ tí ó dárajù, nítorí Olúwa ti ṣe òkun ní ọ̀nà wa, a sì wà lórí erékùṣù òkun kan. Ṣùgbọ́n títóbi ni àwọn ìlérí Olúwa sí àwọn tí mbẹ lórí àwọn erékùṣù òkun; nítorí-èyi bí ó ti sọ pé àwọn erékùṣù, o di dandan ki o ju èyí lọ, àwọn arákùnrin wa sì ngbé nínú wọn pẹ̀lú. Nítorí kíyèsĩ i, Olúwa Ọlọ́run tí tọ́ kúrò láti ìgbà dé ìgbà kúrò ní ará ilé Isráẹ́lì, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti inú dídùn rẹ̀. Àti nísisìyí kíyèsĩ i, Olúwa rántí gbogbo wọn tí a ti ṣẹ́ kúrò, nítorí-èyi ó rántí wa pẹ̀lú. Nítorínã, ẹ mú ọkàn yín yọ̀, kí ẹ sì rántí pé ẹ̀yin ní òmìnira láti ṣe ohunkóhun tìkarãyín—láti yan ọ̀nà ikú àìlópin tàbí ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí-èyi, ẹyin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ ṣe ìlàjà ara yín sí ìfẹ́ Ọlọ́run, kì í sì ṣe sí ìfẹ́ ti èṣù àti ẹran ara; ẹ sì rántí, lẹ́hìn tí ẹ bá ti ṣe ìlàjà sí Ọlọ́run, pé nínú àti nípa ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nìkan ni a gbà yín là. Nítorí-èyi, kí Ọlọ́run jí yín sókè kúrò nínú ikú nípa agbára àjínde òkú, àti pẹ̀lú kúrò nínú ikú àìlópin nípa agbára ètùtù nì, kí á lè gbà yín sí ìjọba ayérayé Ọlọ́run, kí ẹ̀yin kí ó lè yìn ín nípa ore ọ̀fẹ́ ti Ọlọ́run. Àmín. 11 Jákọ́bù rí Olùràpadà rẹ̀—Òfin Mósè ṣe àpẹrẹ Krístì ó sì ṣe ẹ̀rí pé yíò wá. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, Jákọ́bù sọ àwọn ohun púpọ̀ si sí àwọn ènìyàn mi ní àkókò nã; bíótilẹ̀ríbẹ̃ àwọn ohun wọ̀nyí nìkan ni mo mú kí á kọ, nítorí àwọn ohun èyí tí mo ti kọ tó mi. Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kọ àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah si, nítorí ọkàn mi yọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí èmi yíò fi àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wé sí àwọn ènìyàn mi, èmi yíò sì rán wọn jáde lọ sí gbogbo àwọn ọmọ mi, nítorí nítọ́tọ́ ó rí Olùràpadà mi, àní bí èmi ti rí i. Àti arákùnrin mi, Jákọ́bù, ti ríi bí èmi ti ríi pẹ̀lú; nítorí-èyi, èmi yíò rán àwọn ọ̀rọ̀ wọn jáde sí àwọn ọmọ̀ mi láti fi ìdi rẹ̀ múlẹ̀ sí wọn pé àwọn ọ̀rọ̀ mi jẹ́ òtítọ́. Nítorí-èyi, nípa ọ̀rọ̀ ẹni mẹ́ta, Ọlọ́run ti sọ ọ́, ni èmi yíò fi ìdí ọ̀rọ̀ mi mulẹ̀. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Ọlọ́run rán àwọn ẹlẹ́rĩ síi, ó sì fi ìdí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ mulẹ̀. Kíyèsĩ i, ọkàn mí yọ̀ ní síṣe ẹ̀rí sí àwọn ènìyàn mi òtítọ́ bíbọ̀ Krístì; nítorí, fún ìdí èyí ni a ti fi òfin Mósè fún ni; gbogbo àwọn ohun èyí tí a sì ti fi fún ni nípasẹ̀ Ọlọ́run láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, sí ènìyàn, jẹ́ ṣíṣe àpẹrẹ rẹ̀. Àti pẹ̀lú ọkàn mí yọ̀ nínú àwọn májẹ̀mú Olúwa èyí tí ó ti ba àwọn bàbá wa dá; bẹ̃ni, ọkàn mí yọ̀ nínú ore ọ̀fẹ́ rẹ̀, àti nínú àìṣègbè rẹ̀, àti agbára, àti ãnú nínú ìlànà nlá àti ti ayérayé fún ìdásílẹ̀ lọ́wọ́ ikú. Ọkàn mi sì yọ̀ ní síṣe ẹ̀rí sí àwọn ènìyàn mi pé àfi tí Krístì bá wá gbogbo ènìyàn kò lè ṣe àì parun. Nítorí bí kò bá sí Krístì kò sí Ọlọ́run; bí kò bá sì sí Ọlọ́run àwa kò sí, nítorí ìbá má ti sí ẹ̀dá. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan wà, òun sì ni Krístì, òun yíò sì wá ní kíkún àkókò tirẹ̀. Àti nísisìyí mo kọ díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah, kí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn mi tí yíò rí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lè gbé ọkàn wọn sókè kí wọ́n sì yọ̀ fún gbogbo ènìyàn. Nísisìyí ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ nã, ẹ̀yin sì lè fi wọ́n wé sí yín àti sí gbogbo ènìyàn. 12 Isaiah rí tẹ́mpìlì ìgbà-ìkẹhìn, kíkójọ Isráẹ́lì, àti ìdájọ́ òun àlãfíà ti ẹgbẹ̀rún ọdún—Àwọn onígberaga àti àwọn oníwà-búburú ni a ó fà wá sílẹ̀ ní Bíbọ̀ Èkejì–Fi Isaiah 2 wé é. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Ọ̀rọ̀ tí Isaiah, ọmọkùnrin Ámós, rí nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù: Yíò sì ṣe ní àwọn ìgbà ìkẹhìn, nígbàtí a ó fi òkè ilé Olúwa kalẹ̀ lórí àwọn òkè nlá, a ó sì gbée ga ju àwọn òkè kékèké lọ; gbogbo orílẹ̀-èdè ni yíò sì wọ́ sí inú rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yíò sì lọ wọn ó sì wí pé, Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí á lọ sí òkè Olúwa, sí ilé Ọlọ́run Jákọ́bù; òun yíò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwa yíò sì ma rìn ní ipa rẹ̀; nítorí láti Síónì ni òfin yíò ti jáde lọ, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerúsálẹ́mù. Òun yíò sì ṣe ìdájọ́ lãrín àwọn orílẹ̀-èdè, yíò sì bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn wí: wọn yíò sì fi idà wọn rọ irin ọrọ̀ ìtulẹ̀, àti ọ̀kọ̀ wọn sí dòjé—orílẹ̀-èdè kì yíò gbé idà sókè sí orílè-èdè, bẹ́ni wọn kì yíò kọ́ ogun jíjà mọ́. A! ará ilé Jákọ́bù, ẹ wá ẹ sì jẹ́ kí á rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa; bẹ̃ni, ẹ wá, nítorí gbogbo yín ti ṣìnà, olúkúlùkù yín sí àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀. Nítorínã, A! Olúwa, ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, ilé Jákọ́bù, nítorí tí wọ́n kún láti ìlà-oòrùn wá, wọ́n sì fetísílẹ̀ sí aláfọ̀ṣẹ bí àwọn ará Filístínì, wọ́n sì n ṣe inú dídùn nínú àwọn ọmọ àlejò. Ilẹ̀ wọn pẹ̀lú kún fún fàdákà àti wúrà, bẹ̃ni kò sí òpin fún àwọn ìṣura wọn; ilẹ̀ wọn kún fún ẹṣin pẹ̀lú, bẹ̃ni kò sí òpin fún àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn. Ilẹ̀ wọn kún fún àwọn òrìṣà pẹ̀lú; wọ́n nbọ iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn, èyí nì tí ìka àwọn tìkarawọn ti ṣe. Ènìyàn lásán kò sì foríbalẹ̀, ẹni nlá kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, nítorínã, má ṣe dáríjì í. A! ẹ̀yin ẹni búburú, ẹ wọ inú àpáta lọ, kí ẹ sì fi ara yín pamọ́ nínú ekuru, nítorí ìbẹ̀rù Olúwa àti ògo ọlánlá rẹ yíò lù yín. Yíò sì ṣe tí a ó rẹ ìwọ gíga ènìyàn sílẹ̀, a ó sì tẹ orí ìgbéraga ènìyàn bá, Olúwa nìkanṣoṣo ni a ó sì gbé ga ní ọjọ́ nã. Nítorí ọjọ́ Olúwa àwọn Ọmọ-ogun yíò wá láìpẹ́ sí órí orílẹ̀-èdè gbogbo, bẹ̃ni, sí órí olúkúlùkù; bẹ̃ni, sí órí ẹni tí o réra àti tí ó sì gbéraga, àti sórí olúkúlùkù ẹni tí a gbé sókè, òun ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀. Bẹ̃ni, ọjọ́ Olúwa yíò wá sí órí gbogbo igi kédárì Lébánọ́nì, nítorí wọ́n ga a sì gbé wọn sókè; àti sórí gbogbo igi-nlá Báṣánì; Àti sí órí gbogbo òkè gíga, àti sí órí gbogbo òkè kékèké, àti sí órí gbogbo orílẹ̀-èdè tí a gbé sókè, àti sí órí olúkúlùkù ènìyàn; Àti sí órí gbogbo ilé-ìṣọ́ gíga, àti sí órí gbogbo odi; Àti sí órí gbogbo ọkọ̀ òkun, àti sí órí gbogbo ọkọ̀ Tarṣíṣì, àti sí órí gbogbo àwòrán tí ó wuni. A ó sì tẹ orí ìgbéraga ènìyàn balẹ̀, ìréra àwọn ènìyàn ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀; Olúwa nìkanṣoṣo ni a ó sì gbéga ní ọjọ́ nã. Àwọn òrìṣà ni òun yíò sì parẹ́ pátápátá. Wọn yíò sì wọ inú ihò àwọn àpáta lọ, àti inú ihò ilẹ̀, nítoríìbẹ̀rù Olúwa yíò wá sí órí wọn ògo ọlánlá rẹ̀ yíò sì lù wọ́n, nígbàtí ó bá dìde láti mi ilẹ̀ ayé kìjikìji. Ní ọjọ́ nã ènìyàn yíò ju àwọn òrìṣà fàdákà rẹ̀, àti àwọn òrìṣà wúrà rẹ̀, èyí tí ó ti ṣe fún ara rẹ̀ láti máa bọ, sí àwọn èkúté àti sí àwọn àdán; Láti lọ sínú àwọn pàlàpálá àpáta, àti sókè àpáta sísán, nítorí ìbẹ̀rù Olúwa yíò wá sí órí wọn ọlánlá ògo rẹ̀ yíò sì lù wọ́n, nígbàtí ó bá dìde láti mi ilẹ̀ ayé kìjikìji. Ẹ simi lẹ́hìn ènìyàn, ẹ̀mí ẹni tí ó wà ní ihò imú rẹ̀; nítorí nínú kíni a lè kà á sí? 13 Júdà àti Jerúsálẹ́mù ni a ó jẹ níyà fún àìgbọ́ran wọn—Olúwa bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ó sì dájọ́ fun wọn—Àwọn ọmọbìnrin Síónì ni a fi bú tí a sì dá lóró fún ìfẹ́ ayé wọn—Fi Isaiah 3 wé é. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Nítorí kíyèsĩ i, Olúwa, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun, mú kúrò nínú Jerúsálẹ́mù, àti nínú Júdà, ìdádúró àti ọ̀pá, gbogbo ọ̀pá oúnjẹ, àti gbogbo ìdádúró omi— Alágbára ọkùnrin, àti ọkùnrin ogun, onídàjọ́, àti wòlĩ, àti amòye, àti àgbà; Balógun ãdọ́ta, àti ọkùnrin ọlọ́lá, àti olùdámọ́ràn, àti alárèkérekè oníṣọnà, àti alásọdùn tí ó mọ́ ọ̀rọ̀ sọ. Èmi yíò sì fi àwọn ọmọdé fún wọn láti jẹ́ ọmọ-aládé wọn, àwọn ọmọ-ọwọ́ ni yíò sì má a ṣe àkóso wọn. Àwọn ènìyàn ni a ó sì ni lára, olúkúlùkù lọ́wọ́ ẹnìkejì, àti olúkúlùkù lọ́wọ́ aládũgbò rẹ̀; ọmọdé yíò hùwà ìgbéraga sí àgbà, àti àìlọ́lá sí ọlọ́lá. Nígbàtí ènìyàn kan yíò di arákùnrin rẹ̀ ti ilé bàbá rẹ̀ mú, yíò sì wípé: Ìwọ ní aṣọ, máa ṣe alákọ́so wa, kí o má sì jẹ́ kí ìparun yí wá lábẹ́ ọwọ́ rẹ— Ní ọjọ́ nã ni yíò búra, wípé: Èmi kì yíò ṣe oníwòsàn; nítorí ní ilé mi kò sí oúnjẹ tàbí aṣọ; má ṣe fi èmi ṣe alákọ́so àwọn ènìyàn nã. Nítorí Jerúsálẹ́mù di ìparun, Júdà sì ṣubú, nítorí ahọ́n wọn àti ìṣe wọn lòdì sí Olúwa, láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú. Ìwò ojú wọn njẹ́rĩ í sí wọn, ó sì nfi ẹ̀ṣẹ̀ wọn hàn àní bí Sódómù, wọn kò sì lè pa á mọ. Egbé ni fún ọkàn wọn, nítorí wọ́n ti fi ibi san á fún ara wọn! Ẹ sọ fún olódodo pé ó dára fún wọn; nítorí wọn yíò jẹ èso iṣe wọn. Ègbé ni fún ènìyàn búburú, nítorí wọn yíò parun; nítorí èrè ọwọ́ wọn yíò wà lórí wọn! Àti àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọdé ni olùnilára wọn, àwọn obìnrin sì njọba lórí wọn. A! ẹ̀yin ènìyàn mi, àwọn tí ntọ́ ọ sọ́nà mú ọ láti ṣìnà àti láti pa ipa ọ̀nà rẹ run. Olúwa dìde dúró láti sìpẹ̀, ó sì dìde láti dá àwọn ènìyàn nì ẹjọ́. Olúwa yíò lọ sínú ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn àgbà ènìyàn rẹ̀ àti àwọn ọmọ-aládé inú wọn; nítorí ẹ̀yin ti jẹ ọgbà-àjàrà nì run àti ẹrú àwọn tálákà nínú ilé yín. Kíni ẹ̀yin rò? Ẹ fọ́ àwọn ènìyàn mi sí wẹ́wẹ́, ẹ sì fi ojú àwọn tálákà rinlẹ̀, ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Ọmọ-ogun wí. Pẹlupẹlu, Olúwa wípé: Nítorí tí àwọn ọmọbìnrin Síónì gbéraga, tí wọ́n sì nrìn pẹ̀lú ọrùn nína jáde àti ojú ìfẹ́kúfẹ́, tí wọ́n nrìn tí wọ́n sì nyan bí wọ́n ti nlọ, tí wọ́n sì n ró wọ́ro pẹ̀lú ẹsẹ̀ wọn— Nítorínã Olúwa yíò lu adé orí àwọn ọmọbìnrin Síónì pẹ̀lú ẽpá, Olúwa yíò sì jágbọ́n àwọn ipa àṣírí wọn. Ní ọjọ́ nã Olúwa yíò mú ìgboyà àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wọn tí nró wọ́ro kúrò, àti àwọn iweri irun, àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ti o dabi òṣùpá; Àwọn ẹ̀wọ̀n ọ̀ṣọ́, àti àwọn jufù, àti àwọn ìbojú; Àwọn akẹ̀tẹ̀, àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ẹsẹ̀, àti àwọn ọ̀já-orí, àti àwọn ago olọ́rùn dídùn, àti àwọn òrùka etí; Àwọn òrùka, àti ọ̀ṣọ́-imú; Ìpãrọ̀ àwọn aṣọ wíwọ̀, àti àwọn aṣọ ilékè, àti àwọn ìborùn, àti àwọn ìkótí; Àwọn dígi, àti aṣọ ọ̀gbọ dáradára, àti àwọn ìborí, àti àwọn ìbojú. Yíò sì ṣe, dípò ọ́rùn dídùn ọ́rùn búburú yíò wà; àti dípò àmùrè, àkísà; àti dípò irun dídì dáradára, orí pípá; àti dípò ìgbàyà, sísán aṣọ ọ̀fọ̀; ìjóná dípo ẹwà. Àwọn ọkùnrin yín yíò ti ipa idà ṣubú àti àwọn alágbára yín ní ogun. Àwọn ibodè rẹ̀ yíò s ì pohùnréré ẹkún wọn yíò sì ṣọ̀fọ̀; òun yíò sì di ahoro, yíò sì jókó lórí ilẹ̀. 14 Síóni àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ni a ó ràpadà tí a ó sì wẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ ti ẹgbẹ̀rún ọdún—Fi Isaiah 4 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àti ní ọjọ́ nã, obìnrin méje yíò dìmọ́ ọkùnrin kan, wípé: Àwa ó jẹ oúnjẹ ara wa, àwa ó sì wọ aṣọ ara wa; Jẹ́ kí á fi orúkọ rẹ pè wá nìkan láti mú ẹ̀gàn wa kúrò. Ní ọjọ́ nã ni ẹ̀ka Olúwa yíò ní ẹwà tí yíò sì lógo; èso ilẹ̀ yíò ní ọlá yíò sì dára fún àwọn tí ó sálà ní Isráẹ́lì. Yíò sì ṣe, pé, àwọn tí a fi sílẹ̀ ní Síónì tí wọ́n sì kù ní Jerúsálẹ́mù ní a ó pè ní mímọ́, olúkúlùkù ẹni tí a kọ pẹ̀lú àwọn alãyè ní Jerúsálẹ́mù— Nígbàtí Olúwa bá ti wẹ ẹ̀gbin àwọn ọmọbìnrin Síónì nù, tí ó sì ti fọ ẹ̀jẹ̀ Jerúsálẹ́mù kúrò ní ãrín rẹ̀ nípa ẹ̀mí ìdájọ́ àti nípa ẹ̀mí ìjóná. Olúwa yíò sì dá, awọsanma àti ẽfín ní ọ̀sán àti dídán ọ̀wọ́ iná ní òru; ní órí olúkúlùkù ibùgbé òkè Síónì, àti ní órí àwọn àpèjọ rẹ̀, nítorí lórí gbogbo ògo Síónì ni àbò yíò wà. Àgọ́ kan yíò sì wà fún òjìji ní ọ̀sán kúrò nínú ọ́ru, àti fún ibi ìsásí, àti fún ãbò kúrò nínú ìjì àti kúrò nínú òjò. 15 Ọgbà-àjàrà Olúwa (Isráẹ́lì) yíò di ahoro, a ó sì tú àwọn ènìyàn rẹ̀ ká—Ìbànújẹ́ yíò wá sórí wọn ní ipòìṣubú-kúrò nínú òtítọ́ àti títúká wọn—Olúwa yíò gbé ọ̀págun sókè yíò sì kó Isráẹ́lì jọ—Fi Isaiah 5 wée. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nígbànã ni èmi yíò kọ orin sí àyànfẹ́ ọ̀wọ́n mi orin àyànfẹ́ mi ọ̀wọ́n, níti ọgbà-àjàrà rẹ̀. Àyànfẹ́ ọ̀wọ́n mi ní ọgbà-àjàrà lórí òkè eléso. Ó sì sọ ọgbà yí i ká, ó sì ṣa òkúta kúrò nínú rẹ̀, ó sì gbin àṣàyàn àjàrà sí inú rẹ̀, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ sãrin rẹ̀, ó sì ṣe ìfúntí sínú rẹ̀ pẹ̀lú; ó sì wò pé kí ó so èso àjàrà jáde wá, ó sì mú èso àjàrà asodigbó jáde wá. Àti nísisìyí, A! ẹ̀yin olùgbé Jerúsálẹ́mù, àti ẹ̀yin ọkùnrin Júdà, e ṣe ìdájọ́, mo bẹ̀ yín, lãrín mi àti ọgbà-àjàrà mi. Kíni a bá ṣe sí ọgbà-àjàrà mi tí èmi kò ti ṣe nínú rẹ̀? Nítorí-èyi, nígbàtí mo wò pé ìbá mú èso àjàrà jáde wá ó mú èso àjàrà asodigbó jáde wá. Njẹ́ nísisìyí ẹ wá ná; èmi yíò sọ fún yín ohun tí èmi yíò ṣe sí ọgbà-àjàrà mi—èmi yíò mú ọgbà rẹ̀ kúrò, a ó sì jẹ ẹ́ run; èmi yíò sì wó ògiri rẹ̀ lu ilẹ̀, a ó sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀; Èmi yíò si sọ ọ́ di ahoro; a kì yíò tọ́ ẹ̀ka rẹ̀ bẹ̃ni a kì yíò wà á; ṣùgbọ́n ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yíò wá sókè níbẹ̀; èmi yíò sì pàṣẹ fún àwọ̀sánmà kí ó má rọ̀jò sórí rẹ̀. Nítorí ọgbà-àjàrà Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ni ará ilé Isráẹ́lì, àti àwọn ọkùnrin Júdà ni igi-gbíngbìn tí ó wù ú; ó sì retí ìdájọ́, sì kíyèsĩ i, ìnilára; ó retí òdodo, ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, igbe. Ègbé ni fún àwọn tí ó ní ilé kún ilé, títí àyè kò fi sí mọ́, kí wọ́n bà lè nìkan wà ní ãrin ilẹ̀ ayé! Ní etí mi, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun sọ pé, nítọ́tọ́ ọ̀pọ̀ ilé ni yíò di ahoro, àti ìlú nla àti dídára láìsí olùgbé. Bẹ̃ni, ìwọ̀n ákérì mẹ́wã ọgbà-àjàrà yíò mú òṣùwọ̀n bátì kan wá, àti òṣùwọ̀n irúgbìn hómérì kan yíò mú òṣùwọ̀n éfà kan wá. Ègbé ni fún àwọn tí ndìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí wọ́n lè má lépa ọtí líle, tí wọ́n wà nínú rẹ̀ títí di alẹ́, tí ọtí-wáínì sì mú ara wọn gbóná! Àti hárpù, àti fíólì, tábrẹ́tì, àti fèrè, àti ọtí-wáínì wà nínú àsè wọn; ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, bẹ̃ni wọn kò ro iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Nítorínã, àwọn ènìyàn mi lọ sí ìgbèkun, nítorí tí wọn kò ní òye; àwọn ọlọ́lá wọn sì di rírù, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn gbẹ fún òrùngbẹ. Nítorínã, ọ̀run àpãdì ti fún ara rẹ̀ ní àyè, ó sì la ẹnu rẹ̀ ní àìní ìwọ̀n; àti ògo wọn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, àti ọ̀ṣọ́ wọn, àti ẹni tí nyọ̀, yíò sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀. Ènìyàn lásán ni a ó mú wá sílẹ̀, àti ènìyàn alágbára ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, ojú agbéraga ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn Ọmọogun ni a ó gbé ga ní ìdájọ́, àti Ọlọ́run ẹni-mímọ́ yíò jẹ́ mímọ́ nínú òdodo. Nígbànã ni àwọn ọ̀dọ́àgùntàn yíò ma jẹ gẹ́gẹ́bí ìṣe wọn, àti ibi ahoro àwọn tí ó sanra ni àwọn àlejò yíò ma jẹ. Ègbé ni fún àwọn tí nfa ìwà búburú pẹ̀lú okùn ohun asán, àti ẹ̀ṣẹ̀ bí enipé pẹ̀lú okùn kẹ̀kẹ́; Tí wọ́n wípé: Jẹ́ kí ó yára, mú iṣẹ́ rẹ̀ yára, kí àwa kí ó lè rí i; sì jẹ́ kí ìmọ̀ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì súnmọ́ ìhín kí ó sì wá, kí àwa kí o lè mọ̀ ọ́. Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n npe ibi ní rere, àti rere ní ibi, tí nfi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀, àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn, ti nfi ìkorò pe adùn, àti adùn pe ìkorò! Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n gbọ́n ní ojú ara wọn tí wọ́n sì mọ́ òye ní ojú ara wọn! Ègbé ni fún àwọn tí ó ní ipá láti mu ọtí-wáínì, àti àwọn ọkùnrin alágbára láti ṣe àdàlú ọtí líle; Àwọn ẹni tí ó dá àre fún ẹni-búburú nítorí èrè, tí wọ́n sì mú òdodo olódodo kúrò ní ọwọ́ rẹ̀! Nítorínã, bí iná ti í jó àkékù koríko run, tí ọwọ́ iná sì í jó ìyàngbo, egbò wọn yíò dàbí rírà, ìtànná wọn yíò sì gòkè bí eruku; nítorí wọ́n ti ṣá òfin Olúwa àwọn Ọmọ-ogun tì, wọ́n sì ti gan ọ̀rọ̀ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì. Nítorínã, ni ìbínú Olúwa fi ràn sí ènìyàn rẹ̀, ó sì ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí wọn, ó sì ti lù wọ́n; àwọn òkè sì wàrìrì, òkú wọn sì fàya ní ãrin ìgboro. Fún gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀. Yíò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnà, yíò sì kọ sí wọn láti òpin aiyé wá; sì kíyèsĩ i, wọn yíò yára wá kánkán; kò sí ẹnìkan tí yíò ṣe ãrẹ̀ tàbí kọsẹ̀ lãrín wọn. Kò sí ẹni tí yíò tọ́gbé tàbí tí yíò sùn; bẹ̃ni àmùrè ẹ̀gbẹ́ wọn kì yíò tú, bẹ̃ni okùn bàtà wọn kì yíò já; Àwọn ẹni tí ọfà wọn yíò mú, tí gbogbo ọrun wọn sì tẹ̀, a ó ka pátákó ẹṣẹ̀ ẹṣin wọn bí òkúta àkọ̀, àti kẹ̀kẹ́ wọn bí ãjà, ohùn bíbú wọn bí ti kìnìún. Wọn yíò bú ramúramù bí àwọn ọmọ kìnìún; bẹ̃ni, wọn yíò bú ramúramù, wọn yíò sì di ohun ọdẹ nã mú, wọn yíò sì gbé lọ ní àìléwu, kò sì sí ẹnìkan tí yíò gbà sílẹ̀. Àti ní ọjọ́ nã wọn yíò bú ramúramù sí wọn bí bíbú òkun; bí wọ́n bá sì wo ilẹ̀ nã, kíyèsĩ i, òkùnkùn àti ìrora-ọkàn, ìmọ́lẹ̀ sì di òkùnkùn nínú àwòsánmà dúdú rẹ̀. 16 Isaiah rí Olúwa—A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Isaiah jì í—A pè é láti sọ tẹ́lẹ̀—Ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìkọ̀sílẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ Krístì láti ọwọ́ àwọn Jũ—Ìyókù kan yíò padà—Fi Isaiah 6 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Níọdún tí ọba Ussíàh kú, èmi rí Olúwa jóko lórí ìtẹ́ kan, tí ó ga tí ó sì gbé sókè, ìṣẹ́tì aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún tẹ́mpìlì. Lókè rẹ̀ ni séráfù dúró; ọ̀kọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà; pẹ̀lú méjì ó bò o j ú r ẹ̀ , pẹ̀lú m é j ì ó sì bò ẹsẹ̀ rẹ̀, pẹ̀lú méjì ó sì fò. Ìkíní sì ké sí èkejì, ó wípé: Mímọ́, mímọ́, mímọ́, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun; gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀. Àwọn òpó ilẹ̀kùn sì mì nípa ohùn ẹni tí ó ké, ilé nã sì kún fún ẽfín. Nígbànã ni mo wípé: Ègbé ni fún mi! nítorí mo gbé; nítorí tí mo jẹ́ ẹni-aláìmọ́ ètè; mo sì ngbé lãrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè; nítorí tí ojú mi ti rí Ọba nã, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun. Nígbànã ni ọ̀kan nínú àwọn séráfù nã fò wá si ọ́dọ̀ mi, ó ní ẹyin-iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú láti orí pẹpẹ wá; Ó sì fi kàn mí ní ẹnu, ó sì wípé: Kíyèsĩ i, èyí ti kan ètè rẹ; a mú àìṣedẽdé rẹ kúrò, a sì fọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù. Èmi sì gbọ́ ohùn Olúwa pẹ̀lú tí ó wípé: Tani èmi ó rán, àti tani yíò lọ fún wa? Nígbànã ni èmi wípé: Èmi nìyí; rán mi. Òun sì wípé: Lọ kí o sì wí fún àwọn ènìyàn yí—Ẹ gbọ́ nítọ́tọ́, ṣùgbọ́n òye kò yé wọn; ẹ̀yin sì rí nítọ́tọ́, ṣùgbọ́n wọn kò wòye. Mú kí àyà àwọn ènìyàn yí kí ó sébọ́, sì mú kí etí wọn kí ó wúwo, kí o sì dì wọ́n ní ojú—kí wọn kí ó má bá ríran pẹ̀lú ojú wọn, kí wọn má bá sì gbọ́ pẹ̀lú etí wọn, kí wọn má bá sì mọ̀ pẹ̀lú ọkàn wọn, kí a má bá sì yí wọn padà kí a má bá sì mú wọn ní ara dá. Nígbànã ni èmi wípé: Olúwa, yíò ti pẹ́ tó? Ó sì wípé: Títí àwọn ìlú nlá yíò fi di ahoro ní àìsí olùgbé, àti àwọn ilé ní àìsí ènìyàn, àti ilẹ̀ yíò di ahoro pátápátá; Tí Olúwa yíò sì ṣí àwọn ènìyàn nã kúrò lọ réré, nítorí ìkọ̀sílẹ̀ nlá yíò wà ní inú ilẹ̀ nã. Sùgbọ́n síbẹ̀ ìdámẹ́wa yíò wà, wọn yíò sì padà, yíò sì di rírún, bí igi téílì, àti bí igi óákù èyí tí ọpá wà nínú wọn nígbàtí ewé wọn bá rẹ̀; bẹ̃ni èso mímọ́ nã yíò jẹ́ ọpá nínú rẹ̀. 17 Efráímù àti Síríà gbogun ti Júdà—Krístì ni a ó bí láti ọwọ́ wúndíá kan. Fi Isaiah 7 wé é. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe ní àwọn ọjọ́ Áhásì ọmọkùnrin Jótámù, ọmọ kùnrin Ussíàh, ọba Júdà, tí Résínì, ọba Síríà, àti Pékà ọmọkùnrin Remalíàh, ọba Isráẹ́lì, gòkè lọ síhà Jerúsálẹ́mù láti jà á ní ogun, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀. A sì sọ fún ilé Dáfídì, pe: Síríà bá Efráímù dìmọ̀lú. Ọkàn rẹ̀ sì mì, àti ọkàn àwọn ènìyàn rẹ̀, bí igi igbó ti í mì nípa ẹ̀fũfù. Nígbànã ni Olúwa wí fún Isaiah: Jáde lọ nísisìyí láti pádè Áhásì, ìwọ àti Ṣeájáṣúbù ọmọ kùnrin rẹ, ní ìpẹ̀kun ojú ìṣàn ìkùdù ti apá òkè ní òpópó papa afọṣọ; Sì sọ fún un: Kíyèsára, kí o sì gbé jẹ́; má bẹ̀rù, bẹ̃ni kí o máṣe jáya nítorí ìrù méjì igi íná tí nrú ẽfín wọ̀nyí, nítorí ìbínú mímúna Résínì pẹ̀lú Síríà, àti ti ọmọkùnrin Remalíàh. Nítorí Síríà, Efráímù, àti ọmọkùnrin Remalíàh, ti gbìmọ̀ ibi sí ọ, wípé: Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ sí Júdà kí á sì bã nínú jẹ́, ẹ sì jẹ́ kí á ṣe ihò nínú rẹ̀ fún ara wa, kí a sì gbé ọba kan kalẹ̀ lãrín rẹ̀, bẹ̃ni, ọmọ Tábéálì. Báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Kì yíò dúró, bẹ̃ni kì yíò ṣẹ. Nítorí orí Síríà ni Damáskù, àti orí Damáskù, Résínì; nínúọdún márun lé lọgọta ni a ó fọ́ Efráímù tí kì yíò sì jẹ́ ẹ̀yà ènìyàn kan mọ́. Orí Efráímù sì ni Samáríà, orí Samáríà sì ni ọmọ kùnrin Remalìàh. Bí ẹ̀yin kì yíò bá gbàgbọ́ lótitọ́ a kì yíò fi ìdí yín múlẹ̀. Pẹ̀lú-pẹ̀lú, Olúwa tún sọ fún Áhásì, wípé: Bèrè àmì kan lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ; bèrè rẹ̀ ìbá à jẹ́ ní ọ̀gbun, tabí ní ibi gíga jùlọ. Ṣùgbọ́n Áhásì wípé: Èmi kì yíò bere, bẹ̃ni èmi kì yíò dán Olúwa wò. Òun sì wípé: Ẹ gbọ́ nísisìyí A! ará ilé Dáfídì; ṣé ohun kékeré ni fún yín láti dá ènìyàn lágara, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó ha sì dá Ọlọ́run mi lágara pẹ̀lú bí? Nítorínã, Olúwa tìkararẹ̀ yíò fún yín ní àmì kan—Kíyèsĩ i, wúndíá kan yíò lóyún, yíò sì bí ọmọkùnrin kan, yíò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Immánúẹ́lì. Òrí-àmọ́ àti oyin ni yíò ma jẹ, kí ó lè mọ̀ láti kọ ibi àti láti yan ire. Nítorí kí ọmọ nã tó lè mọ̀ láti kọ ibi kí ó sì yan ire, ilẹ̀ ti ìwọ kórìra yíò di ìkọ̀sílẹ̀ lọ́dọ̀ ọba rẹ̀ méjẽjì. Olúwa yíò mú wá sórí rẹ, àti sórí àwọn ènìyàn rẹ, àti sórí ilé bàbá rẹ, àwọn ọjọ́ tí kò tí ì wá láti ọjọ́ tí Efráímù ti lọ kúrò lọ́dọ̀ Júdà, ọba Assíríà. Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã tí Olúwa yíò fẹ́ ẽmí sí eṣinṣin tí ó wà ní apá ìpẹ̀kun Égíptì, àti sí oyin tí ó wà ní ilẹ̀ Assíríà. Wọn yíò sì wá, gbogbo wọn yíò sì bà sínú àfonífojì ijù, àti sínú pàlàpálá òkúta, àti sí órí gbogbo ẹ̀gún, àti sí órí ewéko gbogbo. Ní ọjọ́ kannã ni Olúwa yíò fa-irun pẹ̀lú abẹ tí a yá, ti àwọn ti ìhà kejì odò nì, ti ọba Assíríà, orí, àti irun ẹsẹ̀; yíò sì run irùgbọ̀n pẹ̀lú. Yíò sì ṣe ní ojọ́ nã, ènìyàn kan yíò sì tọ́ ọmọ màlũ kan àti àgùtàn méjì; Yíò sì ṣe, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọ́n yíò mú wá, yíò jẹ òrí-àmọ́; nítorí òrí-àmọ́ àti oyin ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá kù ní ãrin ilẹ̀ nã yíò ma jẹ. Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã, ibi gbogbo yíò dí, ibi tí ẹgbẹ̀rún àjàrà tí wà fún ẹgbẹ̀rún owó fàdákà, èyí tí yíò di ti ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún. Pẹ̀lú ọfà àti ọrún ni ènìyàn yíò wá ibẹ̀, nítorípé gbogbo ilẹ̀ nã yíò di ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún. Àti gbogbo òkè kékèké tí a ó fi ọkọ́ tu, ẹ̀rù ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún kì yíò de ibẹ̀; ṣùgbọ́n yíò jẹ́ fún dída màlũ lọ, àti títẹ̀mọ́lẹ̀ àwọn ẹran kékèké. 18 Krístì yíò jẹ́ bí òkúta ìkọsẹ̀ àti àpáta ẹ̀ṣẹ̀—Ẹ wá Olúwa, kí ì ṣe àwọn oníyọjúsí àjẹ́—Ẹ yí padà sí òfin àti sí ẹ̀rí fun ìtọ́nà—Fi Isaiah 8 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọ̀rọ̀ Olúwa wí fún mi pé: Ìwọ mú ìwé nlá kan, kí o sì kọ̀wé sí inú rẹ̀ pẹ̀lú kálámù ènìyàn, níti Maher-ṣàlál-hàṣ-básì. Èmi sì mú àwọn ẹlẹ́rĩ òtítọ́ sọ́dọ̀ mi láti ṣe ẹlẹ́rĩ, Ùríahàlùfã, àti Sekeríah ọmọkùnrin Jeberekíah. Mo sì wọlé tọ wòlĩ obìnrin nì lọ; ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbànã ni Olúwa wí fún mi pé: Sọ orúkọ rẹ̀ ní, Maherṣàlál-hàṣ-básì. Nítorí kíyèsĩ i,ọmọnã kì yíò ní òye láti ké, Bàbá mi, àti ìyá mi, kí a tó mú ọrọ̀ Damáskù àti ìkógun Samáríà kúrò níwájú ọba Assíríà. Olúwa sì tún wí fún mi, wípé: Níwọ̀n bí ènìyàn yí ti kọ omi Ṣílóà tí nṣàn jẹ́jẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì nyọ̀ nínú Résínì àti ọmọkùnrin Remalíàh. Njẹ́ nítorínã, kíyèsĩ i, Olúwa nfà awọn omi odò wá sórí wọn, tí ó le tí ó sì pọ̀, àní ọba Assíríà àti gbogbo ògo rẹ̀; òun yíò sì wá sórí gbogbo ọ̀nà odò rẹ̀, yíò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀. Òun yíò sì kọjá ní ãrin Júdà; yíò ṣàn bò ó mọ́lẹ̀, yíò sì mù ú dé ọrùn; nína ìyẹ́ rẹ̀ yíò sì kún ìbú ilẹ̀ rẹ, A! Immánúẹ́lì. Ẹ kó ara yín jọ, A! ẹ̀yin ènìyàn, a ó sì fọ́ yín tũtú; ẹ sì fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ará orílẹ̀ èdè jíjìnà; ẹ di ara yín ní àmùrè, a ó sì fọ́ yín tũtú; ẹ di ara yín ní àmùrè, a ó sì fọ́ yín tũtú. Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, yíò sì di asán; ẹ sọ̀rọ̀ nã, kì yíò sì dúró; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa. Nítorí Olúwa wí báyĩ í fún mi pẹ̀lú ọwọ́ agbára, ó sì kọ́ mi kí nmá rìn ní ọ̀nà ènìyàn yí, wípé: Ẹ máṣe sọ pé, Ìdìmọ̀, sí gbogbo awọn tí àwọn ènìyàn yí yio sọ pé, Ìdìmọ̀; bẹ̃ni ẹ máṣe bẹ̀rù ìbẹ̀rù wọn, ẹ má sì ṣe fòyà. Ya Olúwa àwọn Ọmọ-ogun tìkararẹ̀ sí mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ kí ó jẹ ìbẹ̀rù yín, sì jẹ́ kí ó ṣe ìfòyà yín. Òun yíò sì wà fún ibi mímọ́; ṣùgbọ́n fún òkúta ìdìgbòlù, àti fún àpáta ẹ̀ṣẹ̀ sí ilé Isráẹ́lì méjẽjì, fún ẹgẹ́ àti okùn dídẹ sí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn yíò sì kọsẹ̀ wọn yíò sì ṣubú, a ó sì fọ́ wọn, a ó sì dẹ okùn fún wọn, a ó sì mú wọn. Di ẹ̀rí nã, fi èdìdì di òfin nã lãrín àwọn ọmọ-ẹ̀hìn mi. Èmi yíò sì dúró de Olúwa, tí o pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò lára ilé Jákọ́bù, èmi ó sì wã. Kíyèsĩ i, èmi àti àwọn ọmọ tí Olúwa ti fi fún mi wà fún iṣẹ́ àmì àti fún iṣẹ́ ìyanu ní Isráẹ́lì láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wá, tí ngbé Òkè Síónì. Nígbàtí wọ́n yíò bá sì wí fún yín pe: Ẹ wá àwọn ẹ̀mí tí nbá òkú lò, àti àwọn oṣó tí nké tí nsì nkùn—kò ha yẹ kí orílẹ̀-èdè kí ó wá Ọlọ́run wọn ju ki àwọn alãyè ma gbọ́ láti ọ̀dọ̀ òkú bí? Sí òfin àti sí ẹ̀rí; bí wọn kò bá sì sọ gẹ́gẹ́bí ọrọ̀ yí, ó jẹ́ nítorípé kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú wọn. Wọn yíò sì kọjá lãrín rẹ̀ nínú ìnilára àti ebi; yíò sì ṣe pé nígbàtí ebi yíò pa wọ́n, wọn yíò ma kanra, wọn yíò sì fi ọba wọn àti Ọlọ́run wọn ré, wọn yíò sì ma wo òkè. Wọn yíò sì wo ilẹ̀ wọn yíò sì kíyèsĩ ìyọnu, àti òkùnkùn, ìṣújú ítorí àròkàn, a ó sì lé wọn lọ sínú òkùnkùn. 19 Isaiah sọ̀rọ̀ bí i Messia—Àwọn ènìyàn inú òkùnkùn yíò rí ìmọ́lẹ̀nlá—A bí ọmọ kan fún wa—Òun yíò jẹ́ Ọmọ-Aládé Àlãfíà yíò sì jọba lórí ìtẹ́-ọba Dáfídì—Fi Isaiah 9 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ìṣújú nã kì yíò rí gẹ́gẹ́bí ó tí wà ní ìbínú rẹ̀, nígbàtí ní ìṣãjú ó mú ìpọ́njú wá sí ilẹ̀ Sébúlónì jẹ́jẹ́, àti ilẹ̀ Náftálì, àti lẹ́hìnnã o mu ìpọ́njú wá tí ó mú ni kẹ́dùn jùlọ nípa ọ̀nà Òkun Pupa níhà ẹkùn Jordánì ní Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọm ènìyàn tí wọn rìn ní òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ nlá; àwọn tí ngbé ilẹ̀ òjìji ikú, lórí wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí. Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè nì bí sí i púpọ̀-púpọ̀, ìwọ sì sọ ayọ̀ di púpọ̀—wọ́n nyọ̀ níwájú rẹ gẹ́gẹ́bí ayọ̀ ìkórè, àti bí ènìyán ti í yọ̀ nígbàtí wọ́n bá pín ìkógun. Nítorí ìwọ ṣẹ́ àjàgà ìnira rẹ̀, àti ọ̀pá èjìká rẹ̀, ọ̀gọ aninilára rẹ̀. Nítorí gbogbo ìjà àwọn ológun ni ó wà pẹ̀lú ariwo rúdurùdu, àti aṣọ tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀; ṣùgbọ́n èyí yíò jẹ́ fún ìjóná àti igi iná. Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa; ìjọba yíò sì wà ní èjìká rẹ̀; a ó sì ma pe orúkọ rẹ̀ ní, Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára, Bàbá Ayérayé, Ọmọ-Aládé Àlãfíà. Níti ìbísí ìjọba rẹ̀ àti àlãfíà kò sí òpin, lórí ìtẹ́ Dáfídì, àti lórí ìjọba rẹ̀ láti má a tọ́ ọ, àti láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ìdájọ́ àti pẹ̀lú àìsègbè láti ìsisìyí lọ, àní títí láé. Ìtara Olúwa àwọn Ọmọ-ogun yíò ṣe èyí. Olúwa rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí Jákọ́bù ó sì ti bà lé Isráẹ́lì. Gbogbo ènìyàn yíò sì mọ̀, àní Efráímù àti àwọn olùgbé Samáríà, tí nwí nínú ìgbéraga àti líle àyà pé: Awọn bíríkì ṣubù lu ilẹ̀, ṣùgbọ́n àwa ó fi òkúta gbígbẹ́ mọ́ ọ́; a gé igi síkámórè lu ilẹ̀, ṣùgbọ́n a ó fi igi kédárì pãrọ̀ wọn. Nítorínã ni Olúwa yíò gbé àwọn aninilára Résínì dìde sí i, yíò sì da àwọn ọ̀tá rẹ̀ pọ̀; Àwọn ará Síríà níwájú àti àwọn Filístínì lẹ́hìn; wọn yíò sì jẹ Isráẹ́lì run pẹ̀lú ẹnu ṣíṣí. Fún gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀. Nítorí àwọn ènìyàn nã kò yípadà sí ẹni tí ó lù wọ́n, bẹ̃ni wọn kò wá Olúwa àwọn Ọmọ-ogun. Nítorínã ni Olúwa yíò gé kúrò ní Isráẹ́lì orí àti ìrú, ẹ̀ka igi àti koríko-odò ní ọjọ́ kan. Àgbà, òun ni orí; àti wòlĩ tí nkọ́ ni ní èké, òun ni ìrù. Nítorí àwọn olórí ènìyàn yí mú wọn ṣìnà; àwọn tí a sì tọ́ sí ọ̀nà nípa àwọn wọ̀nyí ni a parun. Nítorínã ni Olúwa kì yíò ṣe ní ayọ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́-ọmọkùnrin wọn, bẹ̃ni kì yíò ṣãnú fún àwọn aláìníbaba àti opó wọn; nítorí olúkúlùkù wọn jẹ́ àgàbàgebè àti olùṣe búburú, olúkúlùkù ẹnu sì nsọ wèrè. Fún gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀. Nítorí ìwà-búburú njó bí iná; yíò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run, yíò sì ràn nínú pàntírí igbó, wọn yíò sì gòkè lọ bí gbígbé sókè ẽfín. Nípa ìbínú Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ni ilẹ̀ fi ṣókùnkùn, àwọn ènìyàn yíò dàbí igi iná; ẹnìkan kì yíò dá arákùnrin rẹ̀ sí. Òun yíò sì jájẹ ní ọwọ́ ọ̀tún ebi yíò sì pa á; òun yíò sì jẹ ní ọwọ́ òsì wọn kì yíò sì yó; wọn yíò jẹ olúkúlùkù ènìyàn ẹran-ara apá rẹ̀— Mánássè, Efráímù; àti Efráímù, Mánássè; àwọn méjẽjì yíò dojúkọ Júdà. Fún gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀. 20 Íparun Assíríà jẹ́ àpẹrẹ ìparun ti àwọn ènìyàn búburú ní ìgbà Bíbọ̀ Èkejì—Àwọn ènìyàn díẹ̀ ni a ó fi sílẹ̀ lẹ́hìn tí Olúwa bá tún wá—Ìyókù Jákọ́bù yíò padà ní ọjọ́ nã—Fi Isaiah 10 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Ègbé ni fún àwọn tí npàṣẹ àìṣòdodo, àti tí wọn nkọ ìbànújẹ́ tí wọn ti lànà; Láti yí aláìní kúrò ní ìdájọ́, àti láti mú ohun ẹ̀tọ́ kúrò lọ́wọ́ tálákà ènìyàn mi, kí àwọn opó lè di ìjẹ wọn, àti kí wọ́n bá lè ja aláìníbaba ní olè! Kíni ẹ̀yin yíò sì ṣe lọ́jọ́ ìbẹ̀wò, àti ní ìdáhóró tí yíò ti òkèrè wá? Tani ẹ̀yin yíò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́? Níbo ni ẹ̀yin yíò sì fi ògo yín sí? Láìsí èmi wọn yíò tẹ̀ríba lábẹ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n, wọn yíò sì ṣubú lábẹ́ àwọn tí a pa. Fún gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀. A! Ássíríà, ọ̀gọ́ ìbínú mi, àti ọ̀pá ọwọ́ wọn ni ìrúnú wọn. Èmi ó rán an sí orílẹ-èdè àgàbàgebè, àti sí àwọn ènìyàn ìbínú mi ni èmi ó pàṣẹ kan láti ko ìkógun, àti láti mú ohun ọdẹ, àti láti tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ní ìgboro. Ṣùgbọ́n òun kò rò bẹ̃, bẹ̃ni ọkàn rẹ̀ kò rò bẹ̃; ṣùgbọ́n ó wà ní ọkàn láti parun àti láti gé orílẹ̀-èdè kúrò kĩ ṣe díẹ̀. Nítorí ó wípé: Ọba kọ́ ni àwọn ọmọ-aládé mi ha j ẹ́ pátápátá bí? Kálnò kò ha dàbí Karkemíṣì? Hámátì kò ha dàbí Arpádì? Samáríà kò ha dàbí Damáskù? Gẹ́gẹ́bí ọwọ́ mi ti dá àwọn ìjọba àwọn ère nì, ère èyí tí ó ju ti Jerúsálẹ́mù àti ti Samáríà lọ; Èmi kì yíò ha, bí èmi ti ṣe sí Samáríà àti àwọn ère rẹ̀, ṣe bẹ̃ sí Jerúsálẹ́mù àti àwọn ère rẹ̀ bí? Nítorí-èyi yíò sì ṣe pé nígbàtí Olúwa ti ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ lórí Òkè Síónì àti lórí Jerúsálẹ́mù, èmi yíò bá èso àyà líle ọba Assíríà wí, àti ògo ìwọ gíga rẹ̀. Nítorí ó wípé: Nípa agbára ọwọ́ mi àti nípa ọgbọ́n mi ni èmi ti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí; nítorí èmi mòye; èmi sì ti mú àlà àwọn ènìyàn kúrò, èmi sì ti jí ìṣura wọn, èmi sì ti sọ àwọn olùgbé nã kalẹ̀ bí alágbára ọkùnrin; Ọwọ́ mi sì ti rí bí ìtẹ́ ẹyẹ kan ọrọ̀ àwọn ènìyàn; àti gẹgẹbí ẹní pé ẹnìkan nkó ẹyin tí ó kù jọ ní èmi ti kó gbogbo ayé jọ; kò sí ẹni tí ó gbọn ìyẹ́, tàbí tí ó ya ẹnu, tàbí tí ó dún. Àáké ha lè fọ́nnu sí ẹni tí nfi í la igi? Ayùn ha lè gbé ara rẹ̀ ga sí ẹni tí nmì í? Bí ẹni pé ọ̀gọ lè mi ara rẹ̀ sí àwọn tí ó gbé e sókè, tàbí bí ẹni pé ọ̀pá lè gbé ara rẹ̀ sókè bí ẹni pé kì í ṣe igi! Nítorínã ni Olúwa, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun, yíò rán sí ãrinàwọn tirẹ̀ tí ó sanra, rírù; àti lábẹ́ ògo rẹ̀ yíò dá jíjó kan bí jíjó iná. Ìmọ́lẹ̀ Isráẹ́lì yíò sì jẹ́ iná, àti Ẹní Mímọ́ rẹ̀ yíò jẹ́ ọ̀wọ́-iná, yíò sì jò yíò sì jẹ ẹ̀gún rẹ̀ àti ẹwọn rẹ̀ run ní ọjọ́ kan; Yíò sì jó ògo igbó rẹ̀ run, àti pápá oko eleso rẹ̀, àti ọkàn àti ara; wọn yíò sì dàbí ìgbà tí ọlọ́págún bá dákú. Ìyókù igi igbó rẹ̀ yíò sì jẹ́ díẹ̀, tí ọmọdé yíò lè kọ̀wé wọn. Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã, tí ìyókù Isráẹ́lì, àti irú àwọn tí ó sálà ní ilé Jákọ́bù, kì yíò tún dúró ti ẹni tí ó lù wọ́n mọ́, ṣùgbọ́n wọn yíò duro ti Olúwa, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, ní òtítọ́. Àwọn ìyókù yíò padà, bẹ̃ni, àní àwọn ìyókù ti Jákọ́bù, sí Ọlọ́run alágbára. Nítorí bí ènìyàn rẹ Isráẹ́lì bá dàbí iyanrìn òkun, síbẹ̀ ìyókù nínú wọn yíò padà; àṣẹ ìparun nã yíò kún àkúnwọ́-sìlẹ̀ nínú òdodo. Nítorí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ọmọ-ogun yíò ṣe ìparun, àní ìpinnu ní ilẹ̀ gbogbo. Nítorínã, báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Ọmọ-ogun wí: A! ẹ̀yin ènìyàn mi tí ngbé Síónì, ẹ má bẹ̀rù àwọn ará Assíríà; òun yíò lù ọ́ pẹ̀lú ọ̀gọ, yíò sì gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí ọ, gẹ́gẹ́bí irú ti Égíptì. Nítorí níwọ̀n ìgbà díẹ̀ kíún, ìrunú yíò sì tan, àti ìbínú mi nínú ìparun wọn. Olúwa àwọn Ọmọ-ogun yíò sì gbé pàṣán kan sókè fún un gẹ́gẹ́bí ìpakúpa ti Mídíánì ní àpáta Órébù; àti gẹ́gẹ́bí ọ̀gọ rẹ̀ sójú òkun, bẹ̃ni yíò gbé e sókè gẹ́gẹ́bí irú ti Égíptì. Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã tí a ó gbé ẹrù rẹ̀ kúrò ní èjìká rẹ, àti àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn rẹ, a ó sì pa àjàgà nã run nítorí yíyàn ní àmì òróró. Òun ti dé sí Aíátì, òun ti kọjá sí Mígrónì; ní Míkmaṣì ni òun ti ko ẹrù-ogun rẹ̀ jọ sí. Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà nã; wọ́n ti gba ibùwọ̀ wọn ní Gébà; Rámà bẹ̀rù; Gíbéà ti Saulù ti sá. Gbé ohùn rẹ sókè, A! ọmọbìnrin Gállímù; mú kí á gbọ́ ọ de Láíṣì, A! òtòṣì Anatótì. A yọ Madménà nípò; àwọn olùgbé Gébímù kó ara wọn jọ láti sá. Yíò dúró síbẹ̀ ní Nóbù ní ọjọ́ nã; òun yíò sì mi ọwọ́ rẹ̀ sí òkè gíga ọmọbìnrin Síónì, òkè kékeré Jerúsálẹ́mù. Kíyèsĩ i, Olúwa, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun yíò wọ́n ẹ̀ka pẹ̀lú ẹ̀rù; àti àwọn tí ó ga ní ìnà ni ó gé kúrò; àti àwọn agbéraga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀. Òun yíò sì gé pàntírí igbó lu ilẹ̀ pẹ̀lú irin, Lẹ́bánọ́nì yíò sì ṣubú nípa alágbára kan. 21 Kùkùté Jéssè (Krístì) yíò ṣe ìdájọ́ ní òdodo—Ìmọ̀ Ọ́lọ́run yíò bò ayé ní Ẹgbẹ̀rún-ọdún—Olúwa yíò gbé ọ̀págun sókè yíò sì kó Isráẹ́lì jọ—Fi Isaiah 11 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Ọ̀pa kan yíò sì jáde láti inú kùkùté Jéssè wá, ẹ̀ka kan yíò sì hù jáde láti inú gbòngbò rẹ̀. Ẹ̀mí Olúwa yíò sì bà lée, ẹ̀mí ọgbọ́n àti òye, ẹ̀mí ìgbìmọ̀ àti agbára, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ìbẹ̀rù Olúwa; Yíò sì ṣe é ní òye tãrà ní ìbẹ̀rù Olúwa; òun kì yíò sì dájọ́ nípa ìrí ojú rẹ̀, bẹ̃ni kì yíò dájọ́ nípa gbígbọ́ etí rẹ̀. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yíò ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà, yíò sì báni wi pelu ìṣòtítọ́ fún àwọn ọlọ́kàn tútù ayé; òun yíò sì lu ayé pẹ̀lú ọ̀gọ ẹnu rẹ̀, àti pẹ̀lú ẽmí àwọn ètè rẹ̀ ni òun yíò sì pa àwọn ènìyàn búburú. Òdodo yíò sì jẹ́ àmùrè ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti ìsọ̀títọ́ àmùrè inú rẹ̀. Ìkọ́kò pẹ̀lú yíò ma bá ọ̀dọ́àgùtàn gbé, ẹkùn yíò sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlũ àti ọmọ kìnìún àti ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa papọ̀; ọmọ kékeré kan yíò sì ma dà wọ́n. Àti màlũ àti béárì yíò sì ma jẹ; àwọn ọmọ wọn yíò dùbúlẹ̀ pọ̀; kìnìún yíò sì jẹ koríko bí màlũ. Ọmọ ọmú yíò sì ṣiré ní ihò pãmọ́lẹ̀, ọmọ tí a já lẹ́nu-ọmú yíò sì fi ọ́wọ́ rẹ̀ sí ihò gùnte. Wọn kì yíò panilára bẹ̃ni wọn kì yíò panirun ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí ayé yíò kún fún ìmọ̀ Olúwa, gẹ́gẹ́bí omi ti bò ojú òkun. Àti ní ọjọ́ nã kùkùté Jéssè kan yíò wà, tí yíò dúró fún òpágun àwọn ènìyàn; òun ni àwọn Kèfèrí yíò wá rí; ìsimi rẹ̀ yíò sì ní ògo. Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã tí Olúwa yíò tún nawọ́ rẹ̀ ní ìgbà èkejì láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ ìyókù padà tí yíò kù, láti Assíríà, àti láti Égíptì, àti láti Pátrósì, àti láti Kúṣì, àti láti Elámù, àti láti Ṣínárì, àti láti Hámátì, àti láti àwọn erékùṣù òkun. Òun yíò sì gbé ọ̀págun kan dúró fún àwọn orílẹ̀-èdè, yíò sì gbá àwọn àṣàtì Isráẹ́lì jọ, yíò sì kó àwọn tí a túká ní Júdà jọ láti igun mẹ́rin ayé wá. Ìlara Efráímù yíò lọ kúrò pẹ̀lú, àwọn ọ̀tá Júdà ni a ó sì gé kúrò; Efráímù kì yíò ṣe ìlara Júdà, Júdà kì yíò sì bá Efráímù nínú jẹ́. Ṣùgbọ́n wọn yíò sì fò mọ́ èjìká àwọn Filístínì síhà ìwọ̀oòrùn; wọn yíò jùmọ̀ ba àwọn ti ìlà-oòrùn jẹ́; wọn yíò sì gbé ọwọ́ wọn le Édómù àti Móábù; àwọn ọmọ Ámọ́nì yíò sì gbọ́ràn sí wọ́n lẹ́nu. Olúwa yíò sì pa ahọ́n òkun Égíptì run tũtú; pẹ̀lú ẹ̀fũfù líle rẹ̀ yíò sì mi ọwọ́ rẹ̀ lórí odò nã, ti yíò pín in sí odò ṣíṣàn méje, tí àwọn ènìyàn yíò sì lã kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Ọ̀nà òpópó kan yíò sì wà fún ìyókù àwọn ènìyàn rẹ tí yíò kù, láti Assíríà, gẹ́gẹ́bí ó ti rí fún Isráẹ́lì ní ọjọ́ tí ó gòkè jáde kúrò ní ilẹ̀ Égíptì. 22 Ní ọjọ́ ẹgbẹ̀rún ọdún gbogbo ènìyàn yíò yin Olúwa—Òun yíò gbé ní ãrín wọn—Fi Isaiah 12 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àti ní ọjọ́ nã ìwọ ó wípé: A! Olúwa, èmi yíò yìn ọ́; bíótilẹ̀jẹ́pé ìwọ bínú sí mi ìbínú rẹ ti yí kúrò, ìwọ sì tù mí nínú. Kíyèsĩ i, Ọlọ́run ni ìgbàlà mi; èmi ó gbẹ́kẹ̀lé e, èmi kì yíò sì bẹ̀rù; nítorí Olúwa Jèhófàh ni agbára mi àti orin mi; òun pẹ̀lú ti di ìgbàlà mi. Nítorínã, pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ̀yin yíò fa omi jáde láti inú kànga ìgbàlà wá. Ní ọjọ́ nã ni ẹ̀yin yíò sì wípé: Yin Olúwa, képe orúkọ rẹ̀, sọ àwọn ìṣe rẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn, múu wa sí ìrantí pé orúkọ rẹ̀ ni a gbé lékè. Kọrin sí Olúwa; nítorí ó ti ṣe àwọn ohun dídára; èyí di mímọ̀ ní gbogbo ayé. Kígbe sóde kí o sì hó, ìwọ olùgbe Síónì; nítorí ẹni títóbi ni Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì ní ãrin rẹ. 23 Ìparun Bábílọ́nì jẹ́ irú ìparun ní ìgbà Bíbọ̀ Èkejì—Yíò jẹ́ ọjọ́ ìbínú àti ẹ̀san—Bábílọ́nì (ayé) yíò ṣubú títí láé—Fi Isaiah 13 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àjàgà Bábílọ́nì, èyí tí Isaiah ọmọ Ámósì ọkùnrin rí. Ẹ gbé ọ̀págun sókè lórí òkè gíga, ẹ gbé ohùn ga sí wọn, ẹ ju ọwọ́, kí wọ́n bá lè lọ sínú ẹnu-odi àwọn ọlọ́lá. Èmi ti pàṣẹ fún àwọn tèmi tí a yà sí mímọ́, èmi ti pe àwọn alágbára mi pẹ̀lú, nítorí ìbínú mi kò sí lórí àwọn tí nyọ̀ nínú ọlánlá mi. Ariwo ọ̀pọ̀lọpọ̀ lórí òkè gíga gẹ́gẹ́bí ti ènìyàn púpọ̀, ariwo rúdurùdu ti ìjọba àwọn orílẹ̀èdè tí a kójọ pọ̀, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun gbá ogun àwọn ọmọ ogun jọ. Wọ́n ti orílẹ̀ èdè òkèrè wá, láti ìpẹ̀kun ọ̀run, bẹ̃ni, Olúwa, àti ohun-èlò ìbínú rẹ̀, láti pa gbogbo ilẹ̀ run. Ẹ hó, nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀; yíò dé bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè wá. Nítorínã gbogbo ọwọ́ yíò rọ, àyà olúkúlùkù ènìyàn yíò já; Wọn ó sì bẹ̀rù; ìrora àti ìrora-ọkàn yíò dì wọ́n mú; ẹnu yíò yà ẹnìkan sí ẹnìkejì rẹ̀; ojú wọn yíò dàbí ọ̀wọ́-iná. Kíyèsĩ i, ọjọ́ Olúwa mbọ̀wá, ó ní ibi àti pẹ̀lú ìkọnnú àti ìbínú gbígbóná, láti sọ ilẹ̀ nã di ahoro; òun yíò sì pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ run kúrò nínú rẹ̀. Nítorí àwọn ìràwọ̀ ọ̀run àti ìṣùpọ̀-ìràwọ̀ inú rẹ̀ kì yíò tan ìmọ́lẹ̀ wọn; ọ́rùn yíò ṣòkùnkùn ní ìjádelọ rẹ̀, òṣùpá kì yíò sì mú kì ìmọ́lè rẹ̀ tàn. Èmi ó sì fi ayé jìyà fún ibi, àti àwọn ènìyàn búburú fún àìṣedẽdé wọn; èmi ó mú kí ìgbéraga àwọn agbéraga kí ó mọ, èmi ó sì rẹ ìréra àwọn ènìyàn tí ó banilẹ́rù sílẹ̀. Èmi yíò mú kí ènìyàn kan ṣọ̀wọ́n ju wúrà dídára; àní ènìyàn kan ju wúrà Ófírì dáradára. Nítorínã, èmi ó mú àwọn ọ̀run mì-tìtì, ilẹ̀ ayé yíò sì ṣípò rẹ̀ padà, nínú ìbínú Olúwa àwọn Ọmọ-ogun, àti ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀. Yíò sì dàbí abo àgbọ̀nrín tí à nlépa, àti bí àgùntàn tí ẹnìkan kò gbájọ; olúkúlùkù wọn yíò sì yípadà sí ènìyàn rẹ̀, olúkúlùkù yíò sì sálọ sí ilẹ̀ rẹ̀. Gbogbo ẹni tí ó bá gbéraga ni a ó tanù; bẹ̃ni, gbogbo ẹni tí ó bá da ara pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú ni yíò sì ṣubú nípa idà. Àwọn ọmọ wọn, ni a ó fọ́ tũtú ní ójú ara wọn pẹ̀lú; a ó sì kó wọn ní ilé, a ó sì fi agbára mú àwọn aya wọn. Kíyèsĩ i, èmi ó gbé àwọn ará Médíà dìde sí wọn, tí kì yíò ka fàdákà àti wúrà sí, tí kì yíò sì ní inú dídùn sí i. Ọrún wọn pẹ̀lú yíò fọ́ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tũtú; wọn kì yíò sì ṣe ãnú fún èso inú; ojú wọn kì yíò dá ọmọdé sí. Àti Bábílọ́nì, ògo ìjọba gbogbo, ẹwà ìtayọ Káldéà, yíò dàbí ìgbà tí Ọlọ́run bí Sódómù àti Gòmórrà ṣubú. A kì yíò tẹ̀ ẹ́ dó mọ, bẹ̃ni a kì yíò sì gbé ibẹ̀ mọ́ láti ìran dé ìran: bẹ̃ni àwọn ará Arábíà kì yíò pàgọ́ níbẹ̀ mọ; bẹ̃ni àwọn olùṣọ́-àgùntàn kì yíò kọ́ agbo wọn níbẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n ẹranko ìgbẹ yíò dùbúlẹ̀ níbẹ̀; ilé wọn yíò sì kún fún àwọn ẹ̀dá tí nké; àwọn òwìwí yíò sì ma gbé ibẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ yíò sì ma jó níbẹ̀. Àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti àwọn érékùṣù yíò sì kígbe ní àwọn ilé ahoro wọn, àti drágónì nínú àwọn ãfin wọn tí ó jọjú; ìgbà rẹ̀ sì súnmọ́ etílé, a kì yíò sì fa ọjọ́ rẹ̀ gún. Nítorí èmi yíò pa á run kíákíá; bẹ̃ni, nítorí èmi yíò ní ãnú sí àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yíò parun. 24 A ó ko Isráẹ́lì jọ yíò sì gbádùn ìsimi ẹgbẹ̀rún ọdún—A sọ Lúsíférì sóde kúrò ní ọ̀run fún ìṣọ̀tẹ̀—Isráẹ́lì yíò yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Bábílọ́nì (ayé)—Fi Isaiah 14 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Nítorí Olúwa yíò ṣãnú fún Jákọ́bù, yíò sì tún yan Isráẹ́lì, yíò sì mú wọn gbé ilẹ̀ wọn; àwọn àlejò yíò sì dàpọ̀ mọ́ wọn, wọn yíò sì faramọ́ ilé Jákọ́bù. Àwọn ènìyàn yíò sì mú wọn, wọn yíò sì mú wọn wá sí ãyè wọn; bẹ̃ni, láti ona jijin títí de ìkangun ayé; wọn yíò sì padà sí àwọn ilẹ̀ ìlérí wọn. Ará ilé Isráẹ́lì yíò sì ní wọn, ilẹ̀ Olúwa yíò sì wà fún àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti àwọn ìránṣẹ́-bìnrin; àwọn tí ó ti kó wọn ní ìgbèkun ni wọn yíò kó ní ìgbèkun; wọn yíò sì ṣe àkóso aninilára wọn. Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã tí Olúwa yíò fún ọ ní ìsimi, kúrò nínú ìrora-ọkàn rẹ, àti kúrò nínú ìjáyà rẹ, àti kúrò nínú oko-ẹrú líle níbi tí a ti mú ọ sìn. Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã, ni ìwọ, yio fi ọba Bábílọ́nì ṣe ẹ̀fẹ̀ yí, tí ìwọ yíò sì wípé: Aninilára nì ha ti ṣe dákẹ́, ìlú nlá wúrà dákẹ́! Olúwa ti ṣẹ́ ọ̀pá olùṣebúburú, ọ̀pá-aládé àwọn alákọ́so. Ẹni tí ó fi ìbínú lu àwọn ènìyàn láì dáwọ́ duró, ẹni tí ó fi ìbínú ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè, ni à nṣe inúnibíni sí, láé dẹ́kun. Gbogbo ayé wà ní isimi, wọ́n sì gbé jẹ́; wọ́n bú jáde nínú orin kíkọ. Bẹ̃ni, àwọn igi fírì nyọ̀ sí ọ, àti igi kédárì ti Lébánọ́nì pẹ̀lú, wípé: Láti ìgbà tí ìwọ ti dùbúlẹ̀ kò sí agégi tí ó tọ̀ wá wá. Ọ̀run àpãdì láti ìsàlẹ̀ wá mì fún ọ láti pàdé rẹ ní àbọ̀ rẹ; ó rú àwọn òkú dìde fún ọ, àní gbogbo àwọn alákọ́so ayé; ó ti gbé gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dìde kúrò lórí ìtẹ́ wọn. Gbogbo wọn yíò dáhùn wọn ó sì wí fún ọ pé: Ìwọ pẹ̀lú ti di àìlera gẹ́gẹ́bí àwa bí? Ìwọ ha dàbí àwa bí? Ògo rẹ ni a ti sọ̀kalẹ̀ sí ibójì; a kò gbọ́ ariwo dùrù rẹ; ekòló ti tàn sí ábẹ́ rẹ, ìdin sì bò ọ́ mọ́ ilẹ̀. Báwo ni ìwọ ti ṣe ṣubú láti ọ̀run wá, A! Lúsíférì, ìràwọ̀ òwúrọ̀! A gé ọ lu ilẹ̀, èyí tí ó sọ àwọn orílẹ̀-èdè di aláìlágbára! Nítorí ìwọ ti wí ní ọkàn rẹ: Èmi yíò gòkè lọ sí ọ̀run, èmi yíò gbé ìtẹ́ mi ga kọjá àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run; èmi yíò jòkó pẹ̀lú lórí òkè ìjọ ènìyàn, ní ìhà àríwá; Èmi yíò gòkè kọjá àwọ̀sánmà gíga; èmi yíò dàbí Ọ̀gá-ògo Jùlọ. Síbẹ̀ a ó mú ọ sọ̀kalẹ̀ sí ọ̀run àpãdì, sí awọn ìhà ihò nã. Àwọn tí ó rí ọ yíò tẹjúmọ́ ọ, wọn yíò sì ronú rẹ, wọn yíò sì wípé: Èyí ha nì ọkùnrin nã tí ó mú ayé wárìrì, tí ó mi àwọn ìjọba tìtì? Tí ó sọ ayé dàbí ijù, tí ó sì pa ìlú rẹ̀ run, tí kò sì ṣí ilé àwọn òndè rẹ̀? Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ̃ni, gbogbo wọn, dùbúlẹ̀ nínú ògo, olúkúlùkù nínú ilé rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìwọ ni a gbé sọnù kúrò níbi ibojì rẹ bí ẹ̀ka ìríra, àti ìyókù àwọn tí a pa, tí a fi idà gún ní àgúnyọ, tí nsọ̀kalẹ̀ lọ sí ihò òkúta; bí òkú tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀. A kì yíò sin ọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn, nítorí tí ìwọ ti pa ilẹ̀ rẹ run o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ; irú-ọmọ àwọn olùṣe búburú ni a kì yíò dárúkọ láéláé. Múra ibi pípa fún àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí àìṣedẽdé àwọn bàbá wọn, kí wọn kí ó má bá dìde, tàbí kí wọ́n ní ilẹ̀ nã, tàbí kí wọ́n fi ìlú-nlá kún ojú ayé. Nítorí èmi yíò dìde sí wọn, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, èmi yíò sì gé orúkọ kúrò ní Bábílọ́nì, àti ìyókù, àti ọmọkùnrin, àti ọmọ dé ọmọ, ni Olúwa wí. Èmi yíò sì ṣe é ní ilẹ̀níní fún ọ́rẹ̀, àti àbàtà omi; èmi yíò sì fi ọwọ̀ ìparun gbá a, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí. Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti búra, wípé: Dájúdájú gẹ́gẹ́bí mo ti gbèrò, bẹ̃ni yíò rí; gẹ́gẹ́bí mo ti pinnu, bẹ̃ni yíò sì dúró— Pé èmi ó mú àwọn ará Assíríà ní ilẹ̀ mi wá, àti lórí òkè mi ni èmi yíò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀; nígbànã ni àjàgà rẹ̀ yíò kúrò lára wọn, àti ẹrù rẹ̀ kúrò ní èjìká wọn. Èyí ni ìpinnu tí a pinnu lórí gbogbo ayé; èyí sì ni ọwọ́ tí a nà jáde lórí gbogbo orílẹ̀-èdè. Nítorí Olúwa àwọn Ọmọogun ti pinnu, tani yíò sì sọ ọ́ dí asán? Ọwọ́ rẹ̀ sì nà jáde, tani yíò sì dá a padà? Ní ọdún tí ọba Áhásì kú ni ìnira yí. Ìwọ máṣe yọ̀, gbogbo Filistia, nítorí pàṣán ẹnití ó nà ọ́ ti ṣẹ́; nítorí láti inú gbòngbò ejò ni gùnte kan yíò jáde wá, irúọmọ rẹ̀ yíò sì jẹ́ ejò iná tí nfò. Àkọ́bí àwọn tálákà yíò sì jẹ, àwọn aláìní yíò sì dùbúlẹ̀ láìléwu; èmi yíò sì pa gbòngbò rẹ pẹ̀lú ìyàn, òun yíò sì pa ìyókù rẹ. Hu, A! ẹnu-odi; kígbe, A! ílú; ìwọ, gbogbo Filistia, ti di yíyọ́; nítorí ẽfín yíò ti àríwá jáde wá, ẹnìkan kì yíò sì dá wà ní àkókò yíyàn rẹ̀. Èsì wo ni a ó fi fún àwọn ìránṣẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè? Pé Olúwa ti tẹ Síónì dó, tálákà nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ yíò sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. 25 Nífáì nyọ̀ nínú ìṣe kedere—Àwọn ìsotẹ́lẹ̀ Ìsáíàh yíò yéni ní àwọn ọ́jọ́ ìkẹhìn—Àwọn Jũ yíò padà láti Bábílọ́nì, wọn yíò kan Messia mọ́ àgbélèbú, a ó sì tú wọn ká a ó sì jẹ wọ́n níyà—A ó mú wọn padà sípò nígbàtí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú Messia—Òun yíò wá níṣãjú ní ẹgbẹ̀ta ọdún lẹ́hìn t í Léhì f i Jerúsálẹ́mù sílẹ̀—Àwọn ará Nífáì pa òfin Mósè mọ́ wọ́n sì gbàgbọ́ nínú Krístì, ẹni tí ó jẹ́ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Nísisìyí èmi, Nífáì, sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo ti kọ, èyí tí a ti sọ nípa ẹnu Isaiah. Nítorí kíyèsĩ i, Isaiah sọ àwọn ohun púpọ̀ tí ó le fún púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mi láti mọ̀; nítorí wọn kò mọ̀ nípa irú sísọ-tẹ́lẹ̀ ni ãrín àwọn Jũ. Nítorí èmi, Nífáì, kò tí ì kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nípa íṣe àwọn Jũ; nítorí àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́ àwọn iṣẹ́ òkùnkùn, àwọn ìṣe wọn sì jẹ́ àwọn ìṣe ẹ̀gbin. Nítorí-èyi, mo kọ̀wé sí àwọn ènìyàn mi, sí gbogbo àwọn wọnnì tí yíò gba àwọn ohun wọ̀nyí tí mo kọ lẹ́hìn èyí, kí wọ́n lè mọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run, pé kí wọ́n wá sórí gbogbo orílẹ̀-èdè, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ nã èyí tí ó ti sọ. Nítorí-èyi, ẹ fetísílẹ̀, A! ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ó jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì, kí ẹ sì fi etí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi; nítorí bí àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah kò bá tilẹ̀ ṣe kedere sí yín, bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọ́n ṣe kedere sí gbogbo àwọn wọnnì tí ó kún fún ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n mo fi ìsọtẹ́lẹ̀ kan fún yín, gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí èyí tí mbẹ nínú mi; nítorí-èyi èmi yíò sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìṣe kedere èyí tí ó ti wà pẹ̀lú mi láti ìgbà tí mo ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú bàbá mi; nítorí kíyèsĩ i, ọkàn mi yọ̀ ní ìṣe kedere sí àwọn ènìyàn mi, kí wọ́n lè kọ́ èkọ́. Bẹ̃ni, ọkàn mi sì yọ̀ nínú àwọn ọrọ Isaiah, nítorí mo jáde wá láti Jerúsálẹ́mù, ojú mi sì ti kíyèsĩ àwọn ohun ti àwọn Jũ, mo sì mọ̀ pé àwọn Jũ mọ́ àwọn ohun ti awọn wòlĩ, kò sì sí àwọn ènìyàn míràn tí ó mọ́ àwọn ohun tí a sọ sí àwọn Jũ bí àwọn, àfi tí ó bá jẹ́ pé a kọ́ wọn ní irú ọ̀nà àwọn ohun àwọn Jũ. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, èmi, Nífáì, kò tí ì kọ́ àwọn ọmọ mí ní irú ọ̀nà àwọn Jũ; ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, èmi, tìkarãmi, ti gbé ní Jerúsálẹ́mù, nítorí-èyi mo mọ̀ nípa àwọn agbègbè rẹ̀ yíká; mo sì ti ṣe ìrántí sí àwọn ọmọ mi nípa ìdájọ́ Ọlọ́run, èyí tí ó ti ṣe lãrín àwọn Jũ, sí àwọn ọmọ mi, gẹ́gẹ́bí gbogbo èyí tí Isaiah ti sọ, èmi kò sì kọ wọ́n. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, èmi ntẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìsọtẹ́lẹ̀ tèmi, gẹ́gẹ́bí ìṣe kedere mi; ní èyí tí mo mọ̀ pé ẹnìkan kò lè ṣe àṣìṣe; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ní àwọn ọjọ́ tí a ó mú àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ Isaiah ṣẹ àwọn ènìyàn yíò mọ̀ dájú, ní àwọn àkókò tí wọn yíò ṣe. Nítorí-èyi, wọ́n jẹ́ ìtóye sí àwọn ọmọ ènìyàn, ẹni tí ó bá sì ṣèbí wọn kò jẹ́ bẹ̃, ni èmi yíò bá sọ̀rọ̀ ní pàtàkì, èmi yíò sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ nã sí àwọn ènìyàn tèmi nìkan; nítorí mo mọ̀ pé wọn yíò jẹ́ ìtóye nlá sí wọn ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn; nítorí ní ọjọ́ nãni wọn yíò mọ̀ wọ́n; nitórí-èyi, fún ire wọn ni mo ṣe kọ wọ́n. Bí a sì ti pa ìran kan run lãrín àwọn Jũ nítorí tí àìṣedẽdé, àní bẹ̃ni a ti pa wọ́n run láti ìran dé ìran gẹ́gẹ́bí àìṣedẽdé wọn; a kò sì pa èyíkéyí nínú wọn run rí àfi tí a bá sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlĩ Olúwa. Nítorí-èyi, a ti sọ fún wọn nípa ìparun èyí tí yíò wá sórí wọn, lọ́gán lẹ́hìn tí bàbá mí kúrò ní Jerúsálẹ́mù; bíótilẹ̀ríbẹ̃, wọ́n sé ọkàn wọn le; àti gẹ́gẹ́bí ìsọtẹ́lẹ̀ mi a ti pa wọ́n run, àfi ti àwọn wọnnì tí a mú ní ìgbèkun sínú Bábílọ́nì. Àti nísisìyí èyí ni mo sọ nítorí ti ẹ̀mí tí mbẹ nínú mi. Àti l’áìṣírò a ti mú wọn lọ wọn yíò tún padà, wọn yíò sì jogún ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù; nítorí-èyi, a ó túnmú wọn padà sípò sí ilẹ̀ ìní wọn. Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ i, wọn yíò ní ogun, àti ìró ogun; nígbàtí ọjọ́ nã bá sì wá tí Ọmọ bíbí Kanṣoṣo ti Bàbá, bẹ̃ni, àní Bàbá ọ̀run òun ayé, yíò fi ara rẹ̀ hàn sí wọn ní ẹran ara, kíyèsĩ i, wọn yíò kọ̀ ọ́, nítorí ti àìṣedẽdé wọn, àti líle ọkàn wọn, àti líle ọrùn wọn. Kíyèsĩ i, wọn yíò kàn án mọ́ àgbélèbú; lẹ́hìn tí a bá sì ti gbe ẹ dùbúlẹ̀ ní ibojì fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta òun yíò jínde kúrò nínú òkú, pẹ̀lú ìmúláradá ní ìyẹ́ apá rẹ̀; gbogbo àwọn tí yíò sí gbàgbọ́ ní orúkọ rẹ̀ ní a ó gbà là ní ìjọba Ọlọ́run. Nítorínã, ọkàn mi yọ̀ láti sọ-tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, nítorí mo ti rí ọjọ́ rẹ̀, ọkàn mi sì gbé orúkọ mímọ́ rẹ̀ ga. Sì kíyèsĩ i yíò ṣe pé lẹ́hìn tí Messia bá ti jínde kúrò nínú òkú, tí ó sì ti fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀, sí ọ̀pọ̀ àwọn tí ó bá gbàgbọ́ ní orúkọ rẹ̀, kíyèsĩ i, a ó tún pa Jerúsálẹ́mù run; nítorí ègbé ni fún àwọn tí mbá Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn ìjọ rẹ̀ jà. Nítorí-èyi, a ó tú àwọn Jũ ká lãrín àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo; bẹ̃ni, Bábílọ́nì ni a ó sì parun pẹ̀lú; nítorí-èyi, a ó tú àwọn Jũ ká nípasẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè míràn. Lẹ́hìn tí a bá ti tú wọn ká, tí Olúwa Ọlọ́run sì ti fìyà jẹ wọ́n nípasẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè míràn fún ìwọ̀n àkókò ìran púpọ̀, bẹ̃ni, àní láti ìran dé ìran títí a ó fi yí wọn lọ́kàn padà láti gbàgbọ́ nínú Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, àti ètùtù, èyí tí kò lópin fún gbogbo aráyé—nígbàtí ojọ́ nã yíò sì de tí wọn ó gbàgbọ́ nínú Krístì, tí wọn ó sì sin Bàbá ní orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú ọkàn mímọ́ àti ọwọ́ tí kò ní ẽrí, tí wọn kò wo iwájú mọ́ fún Messia míràn, nígbànã, ní àkókò nã, ọjọ́ nã yíò dé tí yíò di yíyẹ dandan pé kí wọ́n gba àwọn ohun wọ̀nyí gbọ́. Olúwa yíò sì tún ṣe ọwọ́ rẹ̀ ní ìgbà èkejì láti mú àwọn ènìyàn rẹ̀ padà sípò láti ipò wọn tí wọ́n ti sọnù tí wọ́n sì ti ṣubú. Nítorí-èyi, òun yíò tẹ̀ síwájú láti ṣe iṣẹ́ ìyanu àti àjèjì lãrín àwọn ọmọ ènìyàn. Nítorí-èyi, òun yíò mu àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde sí wọn, àwọn ọ̀rọ èyí tí yíò dá wọn lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹhìn, nítorí a ó fi wọ́n fún wọn fún ète yíyí wọn lọ́kàn padà nípa Messia òtítọ́, ẹnití wọ́n kọ̀ sílẹ̀; àti sí yíyí wọn lọ́kàn padà pé wọ́n lè ṣe láé wo iwájú mọ́ fún Messia láti wá, nítorí kò yẹ kí èyíkéyí wá, àfi tí yíò bá jẹ́ Messia èké tí yíò tan àwọnènìyàn jẹ; nítorí àfi Messia kan ni àwọn wòlĩ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Messia nã sì ni ẹni tí àwọn Jũ yíò kọ̀ sílẹ̀. Nítorí gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ, Messia nã mbọ̀wá ní ẹgbẹ̀ta ọdún láti ìgbà tí bàbá mi kúrò ní Jerúsálẹ́mù; àti gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ, àti pẹ̀lú ọ̀rọ̀ angẹ́lì Ọlọ́run nì, orúkọ rẹ̀ yíò jẹ́ Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run. Àti nísisìyí, ẹyin arákùnrin mi, èmi ti sọ̀rọ̀ kedere kí ẹ má bá ṣìṣe. Bí Olúwa Ọlọ́run sì ti mbẹ tí ó mú Isráẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Égíptì, tí ó fi agbára fún Mósè kí ó lè wo áwọn orílẹ̀-èdè nì sàn lẹ́hìn tí àwọn ejò olóró ti bù wọ́n jẹ, bí wọ́n bá gbé ojú wọn sí ejò tí ó gbé dìde sókè níwájú wọn, ó sì fi agbára fún un pẹ̀lú kí ó lu àpáta tí omi sì jáde wá; bẹ̃ni, kíyèsĩ i mo wí fún yín, pé bí àwọn ohun wọ̀nyí ti jẹ́ òtítọ́, àti bí Olúwa Ọlọ́run ti wà lãyè, kò sí orúkọ míràn tí a fi fún ni lábẹ́ ọ̀run àfi ti Jésù Krístì yí, nípa ẹni tí mo ti sọ, nípa èyí tí a ó fi gba ènìyàn là. Nítorí-èyi, nítorí ìdí èyí ni Olúwa Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún mi pé àwọn ohun wọ̀nyí tí mo kọ ni a ó tọ́jú ti a ó sì pamọ́, a ó sì fi lelẹ fún irú-ọmọ mi, láti ìran dé ìran, kí a lè mú ìlérí nã ṣẹ sí Jósẹ́fù, kí irú-ọmọ rẹ̀ má bá parun láé níwọ̀n ìgbàtí ayé bá ṣì dúró. Nítorí-èyi, àwọn ohun wọ̀nyí yíò lọ láti ìran dé ìran níwọ̀n ígbàtí ayé bá ṣì dúró; wọn ó sì lọ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti inú dídùn Ọlọ́run; àwọn orílẹ̀-èdè tí yíò sì ní wọn ni a ó ṣe ìdájọ́ fún nípa wọn gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí a kọ. Nítorí a ṣiṣẹ́ láìsinmi láti kọ̀wé, láti yí àwọn ọmọ wa lọkàn padà, àti àwọn arákùnrin wa pẹ̀lú, láti gbàgbọ́ nínú Krístì, àti láti ṣe ìlàjà sí Ọlọ́run; nítorí a mọ̀ pé nípa ọ́re-ọ̀fẹ́ ni a gbà wá là, lẹ́hìn gbogbo ohun tí a lè ṣe. Àti, l’áìṣírò a gbàgbọ́ nínú Krístì, a pa òfin Mósè mọ́, a sì nwo iwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin sí Krístì, títí a ó fi mú òfin ṣẹ. Nítorí, fún òpin èyí ni a ti fi òfin fún ni; nítorí-èyi òfin nã ti di òkú sí wa, a sì mú wa yè nínú Krístì nítorí ìgbàgbọ́ wa; síbẹ̀síbẹ̀ àwa n pa òfin nã mọ́ nítorí àwọn àṣẹ. A sì nsọ̀rọ̀ nípa Krístì, a nyọ̀ nínú Krístì, a nwãsù nípa Krístì, a nsọ-tẹ́lẹ̀ nípa Krístì, a sì nkọ̀wé gẹ́gẹ́bí àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ wa, kí àwọn ọmọ wa lè mọ́ orísun èwo ni àwọn lè wò fún ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ wọn. Nítorí-èyi, à sọ̀rọ̀ nípa òfin nã kí àwọn ọmọ wa lè mọ́ kíkú òfin nã; àti kí àwọn, nípa mímọ́ kíkú òfin nã, lè wo iwájú sí ìyè nã tí mbẹ nínú Krístì, kí wọ́n sì mọ ìdí tí a fi fúnni ní òfin nã. Lẹ́hìn tí a bá sì mú òfin nã ṣẹ nínú Krístì, wọn ó mọ̀ pé kò yẹ kí wọn sé ọkàn wọn le sí i nígbàtí ó bá to láti pa òfin nã tì. Àti nísisìyí kíyèsĩ i, ẹ̀yin ènìyàn mi, ọlọ́rùn-líle ènìyàn ni yín; nítorí-èyi, mo ti bá a yín sọ̀rọ̀ kedere, tí kò lè sàiyé yin. Àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sì ti sọ yíò dúró bí ẹ̀rí sí yín; nítorí wọ́n to láti kọ́ ẹni kẹ́ni ní ọ̀nà tí ó tọ́; nítorí ọ̀nà tí ó tọ́ ni láti gbàgbọ́ nínú Krístì kí á máṣe sẹ́ ẹ; nítorí nípa sísẹ́ ẹ ẹ̀yin nsẹ́ àwọn wòlĩ àti òfin nã. Àti nísisìyí kíyèsĩ i, mo wí fun yín pé ọ̀nà tí ó tọ́ ni látigbàgbọ́ nínú Krístì, kí á má sì ṣe sẹ́ ẹ; Krístì sì ni Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì; nítorí-èyi ẹ̀yin kò lè ṣe àìwólẹ̀ níwájú rẹ̀, kí ẹ sì sìn ín pẹ̀lú gbogbo agbára, iyè, àti ipá yín, àti gbogbo ọkàn yín; bí ẹ̀yin bá sì ṣe èyí a kì yíò sọ yín sóde bí ó ti wù kí ó rí. Àti, níwọ̀n bí yíò ti jẹ́ títọ́, ẹ̀yin kò lè ṣe àìpa ìṣe àti ìlànà Ọlọ́run mọ́ títí a ó fi mú òfin nã ṣẹ èyí tí a fi fún Mósè. 26 Krístì yíò ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ará Nífáì—Nífáì rí ìparun àwọn ènìyàn rẹ̀ tẹ́lẹ̀—Wọn yíò sọ̀rọ̀ láti inú eruku—Àwọn Kèfèrí yíò kọ́ àwọn ìjọ onígbàgbọ́ èké àti àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn—Olúwa dá àwọn ènìyàn lẹ́kun láti ṣe oyè àlùfã àrékérekè. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Lẹ́hìn ti Krístì yíò sì ti jínde kúrò nínú òkú òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí yín, ẹ̀yin ọmọ mi, àti ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́; àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí yíò sì sọ sí yín yíò jẹ́ òfin tí ẹ̀yin yíò ṣe. Nítorí kíyèsĩ, mo wí fún yín pé mo ti kíyèsĩ pé ọ̀pọ̀ ìran yíò kọjá lọ, àwọn ogun nlá àti ìjà yíò sì wà lãrín àwọn ènìyàn mi. Lẹ́hìn tí Messia nã yíò dé a ó fi àwọn àmì fún àwọn ènìyàn mi nípa ìbí rẹ̀, àti pẹ̀lú nípa ikú àti àjínde rẹ̀; títóbi àti tí ó banilẹ́rù sì ni ọjọ́ nã yíò jẹ́ sí àwọn ènìyàn búburú, nítorí wọn yíò parun; wọn yíò sì parun nítorí wọ́n sọ àwọn wòlĩ sóde, àti àwọn ènìyàn mímọ́, wọn yíò sì sọ wọ́n ní òkúta, wọn yíò sì pa wọ́n; nítorí-èyi igbe ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ yíò gòkè lọ bá Ọlọ́run láti ilẹ̀ sí wọn. Nítorí-èyi, gbogbo àwọn tí ó gbéraga, tí ó sì nṣe búburú, ọjọ́ nã tí mbọ̀wá yíò jó wọn run, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, nítorí wọn yíò dàbí àkékù koríko. Àwọn tí ó sì pa àwọn wòlĩ, àti àwọn ènìyàn mímọ́, ibú ilẹ̀ yíò gbé wọn mì, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí; àwọn òkè nlá yíò sì bò wọ́n, ìjì yíò sì gbé wọn kúrò, àwọn ilé yíò sì wó sórí wọn yíò sì rún wọn sí tũtú yíò sì lọ̀ wọ́n sí ẹ̀tù. A ó sì bẹ wọ́n wò pẹ̀lú àrá, àti mànàmáná, àti àwọn ilẹ̀ ríri, àti irú ìparun gbogbo, nítorí iná ìbìnú Olúwa yíò jó sí wọn, wọn yíò sì dàbí àkékù koríko, ọjọ́ nã tí mbọ̀wá yíò sì fi wọ́n jóná, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí. A! ìrora nã, àti àròkàn ọkàn mi fún ìpàdánù àwọn ènìyàn mi tí a pa! Nítorí èmi, Nífáì, ti rí i, ó sì ti fẹ́rẹ̀ run mí níwájú Olúwa; ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣe àìkígbe sí Ọlọ́run mi: Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ títọ́. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn olódodo tí ó fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ, tí wọn kò sì pa wọ́n run, ṣùgbón tí wọ́n nwo iwájú sí Krístì pẹ̀lú ìdúróṣinṣin fún àwọn àmì tí a fi fún ni, l’áìṣírò ti inúnibíni gbogbo—kíyèsĩ, àwọn ni àwọn tí kì yíò parun. Ṣùgbọ́n Ọmọ Òdodo yíò farahàn sí wọn; òun yíò sì wò wọ́n sàn, wọn yíò sì ní àlãfíà pẹ̀lú rẹ̀, títí ìran mẹ́ta yíò fi kọjá lọ, tí ọ̀pọ̀ nínú ìran ẹ̀kẹ́rin yíò sì ti kọjá lọ nínú òdodo. Nígbàtí àwọn ohun wọ̀nyí bá ti kọjá lọ ìparun kánkán kan mbọ̀wá sórí àwọn ènìyàn mi; nítorí l’áìṣírò ọkàn mi ní ìrora, èmi ti rí i; nítorí-èyi, èmi mọ̀ pé yíò ṣẹ; wọn sì ta ara wọn fún asán; nítorí, fún èrè ìgbéraga wọn àti ẹ̀gọ̀ wọn wọn yíò kórè ìparun; nítorítí wọ́n yọ̣́da fún èṣù tí wọ́n sì yan àwọn iṣẹ́ òkùnkùn sànju ti ìmọ́lẹ̀, nítoríèyi wọn gbọ́dọ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀run àpãdì. Nítorí Ẹ̀mí Olúwa kì yíò bá ènìyàn gbìyànjú nígbà-gbogbo. Nígbàtí Ẹ̀mí bá sì dáwọ́dúró láti bá ènìyàn gbìyànjú nígbànã ni ìparun kánkán yíò dé, èyí sì mú ọkàn mi kẹ́dùn. Bí mo sì tí sọ̀rọ̀ nípa fífi òye yé àwọn Jũ, pé Jésù ni Krístì gan-an, o di dandan ki a fi òye yé àwọn Kèfèrí pẹ̀lú pé Jésù ni Krístì, Ọlọ́run Ayérayé; Àti pé ó fi ara rẹ̀ hàn sí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́; bẹ̃ni, sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn, tí ó nṣe iṣẹ́ ìyanu nlá, àmì àti ìyanu, lãrín àwọn ọmọ ènìyàn gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, mo sọ tẹ́lẹ̀ sí yín nípa àwọn ọjọ́ ìkẹhìn; nípa àwọn ọjọ́ nígbàtí Olúwa Ọlọ́run yíò mú àwọn ohun wọ̀nyí jáde wá sí àwọn ọmọ ènìyàn. Lẹ́hìn tí irú-ọmọ mi àti írú-ọmọ àwọn arákùnrin mi yíò ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́, tí a ó sì ti lù wọ́n nípa ọwọ́ àwọn Kèfèrí; bẹ̃ni, lẹ́hìn tí Olúwa Ọlọ́run yíò ti pa àgọ́ yí wọn ká, tí yíò sì ti gbógun tì wọ́n pẹ̀lú òkè, tí yíò sì gbé àwọn odi sókè sí wọn; àti lẹ́hìn tí a ó ti mú wọn wá sílẹ̀ nínú eruku, àní tí wọn kò sí, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ olódodo ni a ó kọ, àwọn àdúrà àwọn olóotọ́ ni a ó sì gbọ́, a kò sì ní gbàgbé gbogbo àwọn wọnnì tí ó ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́. Nítorí àwọn tí a ó parun yíò bá wọn sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá, ọ̀rọ̀ wọn yíò sì rẹ̀lẹ̀ láti inú eruku wá, ohùn wọn yíò sì dàbí ti ẹnìkan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́; nítorí Olúwa Ọlọ́run yíò fi agbára fún un, kí ó lè sọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́ nípa wọn, àní bí ẹnipé láti ilẹ̀ wá; ọ̀rọ̀ wọn yíò sì dún láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ wá. Nítorí báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Wọn yíò kọ àwọn ohun tí a ó ṣe lãrín wọn, a ó sì kọwọ́n a ó sì fi èdídì dì wọ́n ní ìwé, àwọn wọnnì tí ó ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ kì yíò ní wọn, nítorí wọ́n nwá láti pa àwọn ohun Ọlọ́run run. Nítorí-èyi, bí àwọn ti a ti parun wọnnì ni a ti parun kánkán; àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹni búburú wọn yíò dàbí ìyàngbò tí ó kọjá lọ—bẹ̃ni, báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Yíò rí bẹ̃ nísisìyí, lójijì— Yíò sì ṣe, tí a ó lu àwọn wọnnì tí ó ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ nípa ọwọ́ àwọn Kèfèrí. Àwọn Kèfèrí ni a sì gbé sí okè ní ìgbéraga ojú wọn, wọ́n sì ti kọsẹ̀, nítorí ti títóbi ohun ìkọ̀sẹ̀ wọn, tí wọ́n ti dá ìjọ onígbàgbọ́ púpọ̀ sílẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, wọ́n kẹ́gàn agbára àti iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run, wọ́n sì nwãsù sí ara wọn ọgbọ́n tiwọn àti ẹ̀kọ́ tiwọn, kí wọ́n lè rí èrè kí wọ́n sì lọ̀ sórí ojú àwọn tálákà. Òpọ̀lọ́pọ̀ ìjọ onígbàgbọ́ ni a sì dá sílẹ̀ tí ó nfa ìlara, àti ìjà, àti odì. Àwọn ẹgbẹ̀ òkùnkùn sì wà pẹ̀lú, àní bí ti ìgbà àtijọ́, gẹ́gẹ́bí àwọn ẹgbẹ́ èṣù, nítorí òun ni olùdásílẹ̀ gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí; bẹ̃ni, olùdásílẹ̀ ìpànìyàn, àti àwọn iṣẹ́ òkùnkùn; bẹ̃ni, ó sì fà wọ́n pẹ̀lú okùn rírọ̀ lọ́rùn wọn, títí ìgbà tí ó ti fi dì wọ́n pẹ̀lú okùn líle rẹ̀ títí láé. Nítorí kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi ayanfẹ, mo wí fún yín pé Olúwa Ọlọ́run kì í ṣiṣẹ́ ní òkùnkùn. Òun kì í ṣe ohunkóhun àfi tí ó bá jẹ́ fún èrè ayé; nítorí ó fẹ́ràn ayé, àní tí ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ sílẹ̀ kí ó lé mú gbogbo ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí-èyi, kò pàṣẹ fún ẹníkẹ́ni pé wọn kì yíò pín nínú ìgbàlà rẹ̀. Kíyèsĩ, njẹ́ ó kígbe sí ẹnikẹ́ni, wípé: Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi bi? Kíyèsĩ i, mo wí fún yín, Rárá; ṣùgbọ́n ó wípé: Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin ikangun ayé, ẹ ra wàrà àti oyin, láìsí owó àti láìsí iye. Kíyèsĩ i, òun ha ti pàṣẹ fún ẹnikẹ́ni pé kí wọ́n lọ kúrò nínú àwọn sínágọ́gù, tàbí kúrò ní àwọn ilé ìjọsìn? Kíyèsĩ i, mo wí fún yín, Rárá. Òun ha ti pàṣẹ fún ẹnikẹ́ni pé kí wọ́n má ní ìpín nínú ìgbàlà rẹ̀? Kíyèsĩ i mo wí fún yin, rara; ṣùgbọ́n ó ti fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀fẹ́; ó sì ti pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pe kí wọ́n gba gbogbo ènìyàn níyànjú sí ìrònúpìwàdà. Kíyèsĩ i, Olúwa ha ti pàṣẹ fún ẹnikẹ́ní kí wọ́n má pín nínú ọ́re rẹ̀? Kíyèsĩ i mo wí fún yín, Rárá; ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni ó ní ànfàní ọ̀kan bí ti èkejì, kò sì sí ẹnìkan tí a dá lẹ́kun. Ó pàṣẹ pé kì yíò sí oyè àlùfã àrékérekè; nítorí, kiyesĩ, oyè àlùfã àrékérekè ni pé àwọn ènìyàn nwãsù wọ́n sì gbé ara wọn sókè fún ìmọ́lẹ̀ sí ayé, kí wọ́n lè rí èrè àti ìyìn ayé gbà; ṣùgbọ́n wọn kò wá àlãfíà Síónì. Kíyèsĩ i, Olúwa ti ka ohun yí lẽwọ̀; nítorí-èyi, Olúwa Ọlọ́run ti fi òfin fún ni kí gbogbo ènìyàn kí ó ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ èyí tí nṣe ìfẹ́. Àti pé bí wọn kò bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ asán ni wọ́n. Nítorí-èyi, bí wọn bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ wọn kò ní yọ̣́da fún àwọn àṣiṣẹ́ ní Síónì láti parun. Ṣùgbọ́n àṣiṣẹ́ ní Síónì yíò siṣẹ́ fun Síónì; nítorí bí wọ́n bá siṣẹ́ fun owó wọn yíò parun. Àti pẹ̀lú, Olúwa Ọlọ́run ti pàṣẹ pé kí àwọn aráyé máṣe pànìyàn; kí wọn máṣe purọ́; kí wọn máṣe jalè; kí wọn máṣe pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run wọn lásán; kí wọn má ṣe ìlara; kí wọn máṣe yan odì; kí wọn máṣe bá ara wọn jà; kí wọn máṣe ní ìwà àgbèrè; àti kí wọn má ṣe èyíkéyí nínú àwọn ohun wọ̀nyí; nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe wọn yíò parun. Nítorí èyíkéyí nínú àwọn àìṣedẽdé wọ̀nyí kò wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa; nítorí ó nṣe èyí tí ó dára lãrín àwọn ọmọ ènìyàn; kò sì ṣe ohunkóhun àfi tí ó ṣe kedere sí àwọn ọmọ ènìyàn; ó sì npe gbogbo wọn láti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì pín nínú ọ́re rẹ̀; kò sì kọ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, dúdú àti funfun, tí ó wà nínú ìdè àti ní òmìnira, akọ àti abo; ó sì rántí àwọn abọ̀rìṣà; gbogbo wọn sì dàbí ọ̀kan sí Ọlọ́run, àti àwọn Jũ àti Kèfèrí. 27 Òkùnkùn àti ìṣubú-kuro nínú òtítọ́ yíò bò ayé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn—Ìwé ti Mọ́mọ́nì yíò jáde wá—Àwọn ẹlẹ́rĩ mẹ́ta yíò jẹ́rĩ ìwé nã—Amòye ènìyàn yíò wípé òun kò lè ka ìwé tí a fi èdídì dì—Olúwa yíò ṣe iṣẹ́ ìyanu àti àjèjì—Fi Isaiah 29 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ i, ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, tàbí ní àwọn ọjọ́ àwọn Kèfèrí—bẹ̃ni, kíyèsĩ i gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti àwọn Kèfèrí àti pẹ̀lú àwọn Jũ, àti àwọn tí yíò wá sórí ilẹ̀ yí àti àwọn tí yíò wà lórí àwọn ilẹ̀ míràn, bẹ̃ni, àní lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, kíyèsĩ i, wọn yíò mọtípara pẹ̀lú àìṣedẽdé àti irú ohun ìríra gbogbo— Nígbàtí ọjọ́ nã yíò de a ó bẹ̀ wọ́n wò láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn Ọmọ-ogun, pẹ̀lú ãrá àti pẹ̀lú ilẹ̀ ríri, àti pẹ̀lú ìró nlá, àti pẹ̀lú ìjì, àti pẹ̀lú ẹ̀fũfù, àti pẹ̀lú ọ̀wọ́ ajónirun iná. Gbogbo orílẹ̀-èdè tí sì nbá Síónì jà, tí wọ́n sì pọ́n ọn lójú, yíò dàbí àlá ìran òru; bẹ̃ni, yíò rí bẹ̃ fún wọn, àní bí ẹni ebi npa tí ó nlá àlá, sì kíyèsĩ i ó jẹun ṣùgbọ́n ó jí ọkàn rẹ̀ sì di òfo; tàbí bí ẹni tí òùngbẹ ngbẹ tí nlá àlá, sì kíyèsĩ i ó nmu omi ṣùgbọ́n ó jí sì kíyèsĩ i ó dákú, òùngbẹ sì ngbẹ ọkàn rẹ̀; bẹ̃ni, gẹ́gẹ́ bẹ̃ ni gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yíò rí tí nbá òkè Síónì jà. Nítorí kíyèsĩ i, gbogbo ẹ̀yin tí nṣe àìṣedẽdé, ẹ mú ara dúró kí ẹnu sì yà yín, nítorí ẹ̀yin yíò kígbe sóde, ẹ ó sì kígbe; bẹ̃ni, ẹ̀yin yíò mu àmupara ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú ọtí-wáínì, ẹ̀yin yíò ta gbọ̀ngbọ́n ṣùgbọ́n kí ì ṣe pẹ̀lú ohun mímú líle. Nítorí kíyèsĩ i, Olúwa ti da ẹ̀mí orun jíjìn lù yín. Nítorí kíyèsĩ i, ẹ̀yin ti pa ojú yín dé, ẹ sì ti kọ àwọn wòlĩ sílẹ̀; àti àwọn olórí yín, àti àwọn aríran ni ó ti bò ní ojú nítorí ti àìṣedẽdé yín. Yíò sì ṣe tí Olúwa Ọlọ́run yíò mú jáde sí yín àwọn ọ̀rọ̀ ìwé kan, wọn yíò sì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wọnnì tí ó ti tọ́gbé. Sì kíyèsĩ i a ó fi èdídì di ìwé nã; nínú ìwé nã sì ni ìfihan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run yíò wà, láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé titi de òpin rẹ̀. Nítorí-èyi, nítorí ti àwọn ohun tí a fi èdídì dì pọ̀, a kì yíò jọ̀wọ́ àwọn ohun tí a fi èdídì dì ní ọjọ́ ìwà búburú àti ẹ̀gbin àwọn ènìyàn. Nítorí-èyi a ó pa ìwé nã mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n a ó jọ̀wọ́ ìwé nã fún ọkùnrin kan, òun yíò sì fún ni ní àwọn ọ̀rọ̀ ìwé nã, èyí tí nṣe àwọn ọ̀rọ̀ àwọn ẹni tí ó ti tọ́gbé nínú eruku, òun yíò sì fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún òmíràn. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí a fi èdídì dì òun kì yíò fi fún ni, bẹ̃ni kì yíò fi ìwé nã fún ni. Nítorí a ó fi èdídì di ìwé nã nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run, ìfihàn èyí tí a sì fi èdídì dì ni a ó pamọ́ sínú ìwé nã títí di àkókò títọ́ ti Olúwa, kí wọ́n lè jáde wá; nítorí kíyèsĩ i, wọ́n fi ohun gbogbo hàn láti ìpìlẹ̀ ayé dé òpin rẹ̀. Ọjọ́ nã sì mbọ̀wá tí a ó ka àwọn ọ̀rọ̀ ìwé èyí tí a fi èdídì dì lórí àwọn òkè ilé; a ó sì kà wọ́n nípa agbára Krístì; a ó sì fi ohun gbogbo hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn tí ó ti wà lãrín àwọnọmọ ènìyàn, àti tí yíò wà láé àní dé òpin ayé. Nítorí-èyi, ní ọjọ́ nã nígbàtí a ó fi ìwé nã fún ọkùnrin nã nípa ẹni tí mo ti sọ̀, a ó fi ìwé nã pamọ́ kúrò ní ojú ayé, tí ojú ẹnikẹ́ni kì yíò ríi àfi pé àwọn ẹlẹ́rĩ mẹ́ta yíò ríi, nípa agbára Ọlọ́run, pẹ̀lú ẹni tí a ó fi ìwé nã fún; wọn yíò sì jẹ́rĩ sí òtítọ́ ìwé nã àti àwọn ohun inú rẹ̀. Kò sì sí ẹnikẹ́ni míràn tí yíò wò ó, àfi àwọn díẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ Ọlọ́run, láti sọ ẹ̀rí nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyán; nítorí Olúwa Ọlọ́run ti sọ pé kí àwọn ọ̀rọ̀ olóotọ́ kí ó sọ̀rọ̀ bí ẹni pé ó wá láti òkú. Nítorí-èyi, Olúwa Ọlọ́run yíò tẹ̀ síwájú láti mú àwọn ọ̀rọ̀ iwé nã jáde wá; ní ẹnu ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́rĩ tí ó básì ṣe bí ẹnipé ó dára ni yíò ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀; ègbé sì ni fún ẹni nã tí yíò kọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀! Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, yíò ṣe tí Olúwa Ọlọ́run yíò wí fún ẹni tí oun yíò fi ìwé nã fun: Mú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a kò fi èdídì dì kí o sì fi wọ́n fún ẹlòmíràn, kí ó lè fi wọ́n hàn fún amòye, wípé: Ka èyí, èmi bẹ̀ ọ́. Amòye nã yíò sì wípé: Mú ìwé nã wá síhín, èmi yíò sì kà wọ́n. Àti nísisìyí, nítorí ògo ti ayé àti láti rí èrè gbà ni wọn yíò fi sọ èyí, kì í sì ṣe fún ògó Ọlọ́run. Ọkùnrin nã yíò sì wípé: Èmi kò lè mú ìwé nã wá, nítorí a fi èdídì dì í. Nígbànã ni amòye nã yíò wípé: Èmi kò lè kà á. Nítorí-èyi yíò ṣe, tí Olúwa Ọlọ́run yíò tún fi ìwé nã àti àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ fún ẹni tí ki i ṣe amòye; ẹni tí ki i ṣe amòye nã yíò wípé: Èmi ki i ṣe amòye. Nígbànã ni Olúwa Ọlọ́run yíò wí fún un: Àwọn amòye kì yíò kà wọ́n, nítorí wọ́n ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀, èmi sì lè ṣe iṣẹ́ tèmi; nítorí-èyi ìwọ yíò ka àwọn ọ̀rọ̀ nã tí èmi yíò fi fún ọ. Máṣe fi ọwọ́ kan àwọn ohun èyí tí a fi èdídì dì, nítorí èmi yíò mú wọn jáde wá ní àkókò tí ó tọ́ ní tèmi; nítorí èmi yíò fihàn sí àwọn ọmọ ènìyàn pé èmi lè ṣe iṣẹ́ tèmi. Nítorí-èyi, nígbàtí ìwọ bá ti ka àwọn ọ̀rọ̀ tí mo ti pàṣẹ fún ọ, tí o sì gba àwọn ẹlẹ́rĩ èyí tí mo ti ṣe ìlérí fún yín, nígbànã ni ìwọ yíò tún fi èdídì di ìwé nã, ìwọ yíò sì fi pamọ́ fún mi, kí èmi lè pa àwọn ọ̀rọ̀ tí ìwọ kò tí ì kà mọ, títí èmi yíò ri pé ó tọ́ ní ọgbọ́n tèmi láti fi ohun gbogbo hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn. Nítorí kíyèsĩ i, èmi ni Ọlọ́run; èmi sì jẹ́ Ọlọ́run àwọn iṣẹ́-ìyanu; èmi yíò fi hàn sí ayé pé èmi jẹ́ ọ̀kannã ní àná, ní òní, àti títí láé; èmi kì yíò sì ṣe iṣẹ́ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn àfi tí ó bá jẹ́ gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn. Yíò sì tún ṣe tí Olúwa yíò wí fún ẹni tí yíò ka àwọn ọ̀rọ̀ nã tí a ó fi fún un: Níwọ̀n bí àwọn ènìyàn yí ti nfi ẹnu wọn fà mọ́ mi, tí wọ́n sì nfi ètè wọn yìn mí, ṣùgbọ́n tí ọkàn wọn jìnà sí mi, tí wọ́n sì bẹ̀rù mi nípa ìlànà ènìyàn— Nítorí-èyi, èmi yíò tẹ̀síwájú láti ṣe iṣẹ́ ìyanu lãrín àwọn ènìyàn, bẹ̃ni, iṣẹ́ ìyanu àti àjèjì, nítorí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n àti tí amòye wọn yíò parun, òye àwọn amero wọn yíò sì lùmọ́. Ègbé sì ni fún àwọn tí nwá ọ̀nà láti fi ìmọ̀ràn wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa! Iṣẹ́ wọn sì wà ní òkùnkùn; wọ́n sì wípé: Tani ó rí wa, taní ó sì mọ̀ wá? Wọ́n sì wí pẹ̀lú pé: Dájúdájú, yíyí àwọn ohun po ní a ó kà sí bí amọ̀ amọ̀kòkò. Ṣugbọn kíyèsĩ i, èmi yíò fí hàn wọ́n, ní Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, pé èmi mọ́ gbogbo iṣẹ́ wọn. Nítorí iṣẹ́ yíò ha wí fún ẹni tí ó ṣe é pé, òun kò ṣe mí? Tàbí ohun tí a mọ́ yíò ha wí fún ẹni tí ó mọ́ ọ́ pé, òun kò mòye? Sùgbọ́n kíyèsĩ i, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí: Èmi yíò fi hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn pé ó ku ìgbà díẹ̀ kíún síi Lébánọ́nì yíò sì di pápá eléso; pápá eléso nã ni a ó sì kà sí bí igbó. Ní ọjọ́ nã sì ni odi yíò gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé nã, ojú afọ́jú yíò sì rí láti inú ìfarasin àti láti inú òkùnkùn. Àti ọlọ́kàn tútù pẹ̀lú yíò pọ̀si, ayọ̀ wọn yíò sì wà nínú Olúwa, àwọn tálákà lãrín àwọn ènìyàn yíò sì yọ̀ nínú Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì. Nítorí dájúdájú bí Olúwa ti wà lãyè, wọ́n yíò ri pé a sọ ẹni búburú nã di asán, àwọn ẹlẹ́gàn ni a ó sì jẹ run, gbogbo àwọn tí nwá àìṣedẽdé ni a ó sì gé kúrò; Àti àwọn tí ó nsọ ènìyàn di òdaràn nípa ọ̀rọ̀, tí wọn sì tọ́ èbìtì fún ẹni tí ó báni wí ní ẹnu ọ̀nà òde, tí wọ́n sì yí èyítí ó tọ́ sí ápákan fún ohun asán. Nítorí-èyi, báyĩ ni Olúwa wí, ẹni tí ó ra Ábráhámù padà, nípa ilé Jákọ́bù: Jákọ́bù kì yíò tijú báyĩ, bẹ̃ni ojú rẹ̀ kì yíò di funfun. Ṣùgbọ́n nígbàtí òun yíò rí àwọn ọmọ rẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ mi, ní ãrin rẹ̀, wọn yíò ya orúkọ mi sí mímọ́, wọn yíò sì ya Ẹní Mímọ́ Jákọ́bù sí mímọ́, wọn yíò sì bẹ̀rù Ọlọ́run Isráẹ́lì. Àwọn nã pẹ̀lú tí o ṣìnà ní ẹ̀mí yíò wá sí ìmọ̀, àwọn tí ó nkùn sínú yíò kọ́ ẹ̀kọ́. 28 Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìjọ onígbàgbọ́ èké ní a o dá sílẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn—Wọn yíò kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ayédèrú, tí ó wà lásán, àti tí ó jẹ́ tí aláìgbọ́n—Ìṣubú-kúrò nínú òtítọ́ yíò di púpọ̀ nítorí àwọn ayédèrú olùkọ́—Èṣù yíò rú ní ọkàn àwọn ènìyàn—Òun yíò kọ́ irú àwọn ẹ̀kọ́ ayédèrú gbogbo. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi ti sọ̀rọ̀ sí yín, gẹ́gẹ́bí Ẹ̀mí ti rọ̀ mí; nítorí-èyi, èmi mọ̀ pé wọn kò lè ṣe àìṣẹ. Àwọn ohun èyí tí a ó sì kọ láti inú ìwé nã yíò jẹ́ tí iye nlá sí àwọn ọmọ ènìyàn, àti pãpã sí irú-ọmọ wa, èyí tí i ṣe ìyókù ará ilé Ísráẹ́lì. Nítorí yíò ṣe ní ọjọ́ nã tí àwọn ìjọ onígbàgbọ́ tí a fi lélẹ̀, tí kì í sì í ṣe sí Olúwa, nígbàtí ọ̀kan yíò wí fún òmíràn: Kíyèsĩ i, èmi, èmi ni ti Olúwa; àwọn òmíràn yíò sì wí pé: Èmi, èmi ni ti Olúwa; báyĩ sì ni olúkúlùkù ẹni yíò sọ tí ó ti fi àwọn ìjọ onígbàgbọ́ lélẹ̀, ti kì í sì í ṣe sí Olúwa— Wọn yíò sì bá ara wọn jiyàn; àwọn àlùfã wọn yíò sì bá ara wọn jiyàn, wọn yíò sì kọ́ni pẹ̀lúẹ̀kọ́ wọn, wọn yíò sì sẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí nfi ọ̀rọ̀-sísọ fún ni. Wọ́n sì sẹ́ agbára Ọlọ́run, Ẹní Mímọ́ Ísráẹ́lì; wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn: Ẹ fetísílẹ̀ sí wa, kí ẹ sì gbọ́ ìlànà wa; nítorí kíyèsĩ i kò sí Ọlọ́run ní òní, nítorí Olúwa àti Olùràpadà ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, ó sì ti fi agbára rẹ̀ fún ènìyàn; Kíyèsĩ i, ẹ fetísílẹ̀ sí ìlànà mi; bí wọn yíò bá wípé iṣẹ́ ìyanu wà tí a ti ṣe nípa ọwọ́ Olúwa, ẹ máṣe gbà á gbọ́; nítorí ní ọjọ́ yí òun ki í ṣe Ọlọ́run ti iṣẹ́ ìyanu; òun ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Bẹ̃ni, ọ̀pọ̀ ni yíò sì wà tí yíò wípé: Ẹ jẹ́, ẹ mu, kí ẹ sì máa yọ̀, nítorí ní ọ̀la àwa yíò kú; yíò sì dára fún wa. Ọ̀pọ̀ ni yíò sì wà pẹ̀lú tí yíò wípé; ẹ jẹ, ẹ mu, kí ẹ sì máa yọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run—òun yíò dá yín láre ni dídá ẹ̀ṣẹ̀ kékeré; bẹ̃ni, purọ́ kékeré, jẹ ànfàní ẹnìkan nítorí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, gbẹ́ kòtò fún aládũgbò rẹ; kò sí ibi nínú èyí; sì ṣe gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí, nítorí ní ọ̀la àwa yíò kú; bí ó bá sì jẹ́ pé àwa jẹ̀bi, Ọlọ́run yíò nà wá pẹ̀lú pàṣán díẹ̀, ní ìgbẹ̀hìn a ó sì gbà wá là ní ìjọba Ọlọ́run. Bẹ̃ni, ọ̀pọ̀ ni yíò sì wà tí yíò kọ́ni bí irú èyí, àwọn ẹ̀kọ́ ayédèrú àti tí ó wà lásán àti tí ó jẹ́ ti aláìgbọ́n, wọn yíò sì fẹ̀ sókè ní ọkàn wọn, wọn yíò sì gbìyànjú gidi láti pa ìmọ̀ràn wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ Olúwa; iṣẹ́ wọn yíò sì wà ní òkùnkùn. Ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ yíò sì kígbe látí ilẹ̀ wá sí wọn. Bẹ̃ni, gbogbo wọ́n tí jáde kúrò ní ọ̀nà nã; wọ́n ti dibàjẹ́. Nítorí ìgbéraga, àti nítorí àwọn ayédèrú olùkọ́, àti ayédèrú ẹ̀kọ́, àwọn ìjọ onígbàgbọ́ wọn ti dibàjẹ́, àwọn ìjọ onígbàgbọ́ wọn sì gbé sókè; nítorí ti ìgbéraga wọ́n ní wọ́n fẹ̀ sókè. Wọ́n ja tálákà ní olè nítorí ti ibi mímọ́ dídára wọn; wọ́n ja tálákà ní olè nítorí aṣọ dídára wọ́n; wọ́n sì ṣe inúnibíni sí ọlọ́kàn tútù àti oníròbìnújẹ́-ọkànènìyàn, nítorí nínú ìgbéraga wọ́n ní wọ́n fẹ̀ sókè. Wọ́n wọ ọrùn líle àti orí gíga; bẹ̃ni, àti nítorí ìgbéraga, àti ìwà búburú, àti ohun ìríra, àti ìwà àgbèrè, gbogbo wọn ti ṣáko lọ àfi tí ó jẹ́ díẹ̀, tí wọn jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Krístì tí wọ́n nírẹ̀lẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a tọ́ wọn, pé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà wọ́n ṣìnà nítorí a kọ́ wọn nípasẹ̀ ìlànà ti ènìyàn. A! àwọn ọlọgbọ́n, àti àwọn amòye, àti àwọn ọlọ́rọ̀, tí wọ́n fẹ̀ sókè ní ìgbéraga ọkàn wọn, àti gbogbo àwọn tí nwãsù àwọn ayédèrú ẹ̀kọ́, àti gbogbo àwọn tí wọ́n nhu ìwà àgbèrè, tí wọ́n nyí òtítọ́ ọ̀nà Olúwa padà, ègbé, ègbé, ègbé ni fún wọn, ni Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè wí, nítorí a ó tì wọ́n sísàlẹ̀ sí ọ̀run àpãdì! Ègbé ni fún àwọn tí nyí èyítí ó tọ́ sí ápákan fún ohun asán tí wọ́n sì nkẹ́gàn sí èyí tí ó dára, tí wọ́n sì nsọ pé kò ní iye lórí! Nítorí ọjọ́ nã yíò dé tí Olúwa Ọlọ́run yíò bẹ àwọn olùgbé ayé wò kíákíá; ní ọjọ́ nã tí wọ́n bá sì ti gbó nínú àìṣedẽdé ní kíkún wọn yíò parun. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, bí àwọn olùgbé ayé bá ronúpìwàdà níti ìwà búburú àti ìríra wọn a kì yíò pa wọ́n run, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára, àgbèrè gbogbo ayé, kò lè ṣe àìsubú sí ilẹ̀, títóbi sì ni ìṣubú rẹ̀ yíò jẹ́. Nítorí ijọba èṣù gbọdọ̀ mì, àwọn tí ó bá sì jẹ́ tirẹ̀ ni ó di dandan pé kí á rú sókè sí ìrònúpìwàdà, bíbẹ̃kọ́ èṣù yíò gbá wọn mú pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n àìlópin rẹ̀, a ó sì rú wọn sókè sí ìbínú, wọn yíò sì parun; Nítorí kíyèsĩ i, ní ọjọ́ nã ní òun yíò rú ní ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn, tí yíò sì rú wọn sókè sí ìbínú sí èyí tí ó dára. Àwọn míràn sì ni òun yíò rọ̀, tí yíò sì mú wọn dákẹ́ sínú àbò ti ara, tí wọn yíò wípé: Gbogbo rẹ̀ dára ní Síónì; bẹ̃ni Síónì ṣe rere, gbogbo rẹ̀ dára—báyĩ sì ni èṣù nyan ọkàn wọn jẹ, ó sì tọ́ wọn lọ sísàlẹ̀ lẹ́sọ̀lẹsọ̀ sí ọ̀run àpãdì. Sì kíyèsĩ i, àwọn míràn ni ó tàn lọ, tí ó sì sọ fún pé kò sí ọ̀run-àpãdì; òun sì wí fún wọn: Èmi kì í ṣe èṣù, nítorí kò sí ọ̀kan—báyĩ sì ni ó sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́ ní etí wọn, títí o fi gbá wọn mú pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n rẹ̀ tí ó báni lẹ́rù, láti ibi tí kò sì ìdásílẹ̀. Bẹ̃ni, a gbá wọn mú pẹ̀lú ikú, àti ọ̀run àpãdì; àti ikú, àti ọ̀run àpãdì, àti èṣù, àti gbogbo èyí tí a mú ní ipá níbẹ̀ pẹ̀lú gbọ́dọ̀ dúró níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, kí á sì dá wọn léjọ́ gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ wọn, láti ibi tí wọn gbọ́dọ̀ lọ sínú ibi tí a pèsè fún wọn, àní adágún iná àti imí ọjọ́, èyí tí nṣe oró àìnípẹ̀kun. Nítorí-èyi, ègbé ni fún ẹni nã tí ó wà ní ìrọra ní Síónì! Ègbé ni fún ẹni nã tí ó nkígbe: Gbogbo rẹ̀ dára! Bẹ̃ni, ègbé ni fún ẹni nã tí ó fetísílẹ̀ sí ìlànà àwọn ènìyàn, tí ó sì sẹ́ agbára Ọlọ́run, àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́! Bẹ̃ni, égbé ni fún ẹni nã tí ó wípé:Àwa ti gbà, àwa kò sì fẹ́ mọ́! Àti ní àkópọ̀, ègbé ni fún gbogbo àwọn tí nwárìrì, tí wọ́n sì nbínú nítorí òtítọ́ Ọlọ́run! Nítorí kíyèsĩ i, ẹni tí a kọ́ sórí àpáta gbà á pẹ̀lú inúdídùn; ẹni tí a sì kọ́ sórí ìpìlẹ̀ tí ó ní yanrìn nwárìrì kí ó má bá a ṣubú. Ègbé ni fún ẹni nã tí yíò wípé: Àwa ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwa kò sì fẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sĩ; mọ́, nítorí a ní tó! Nítorí kíyèsĩ i, báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èmi yíò fi fún àwọn ọmọ ènìyàn lẹ́sẹ lẹ́sẹ ilànà lé ìlànà, díẹ̀ níhin, díẹ̀ lọ́hún; alábùkún-fún sì ni àwọn tí ó bá fetísílẹ̀ sí ẹ̀kọ́ mi, tí wọ́n sì ya etí wọn sí ìmọ̀ràn mi, nítorí wọn yíò kọ́ ọgbọ́n; nítorí ẹni tí ó gbà ni èmi yíò fi fún sĩ; àti láti ọwọ́ àwọn tí yíò wípé, Àwa ní tó, láti ọwọ́ wọn ni a ó ti gba àní èyí tí wọ́n ní kúrò. Ìfibú ni ẹni tí o gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn, tàbí tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe apá rẹ̀, tàbí tí yíò fetísílẹ̀ sí ìlànà àwọn ènìyàn, àfi tí a bá fi ìlànà wọn fún ni nípa Ẹ̀mí Mímọ́. Ègbé ni fún àwọn Kèfèrí, ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Ọmọ-ogun wí! Nítorí l’áìṣírò èmi yíò na ọwọ́ mi jáde sí wọn láti ọjọ́ dé ọjọ́, wọn yíò sẹ́ mi; bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi yíò ní ãnu sí wọn, ni Olúwa Ọlọ́run wí, bí wọ́n yíò bá ronúpìwàdà tí wọn wá sọ́dọ̀ mi; nítorí ọwọ́ mi nà sóde ní gbogbo ọjọ́, ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Ọmọ-ogun wí. 29 Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn Kèfèrí ni yíò kọ Ìwé ti Mọ́mọ́nì sílẹ̀—Wọn yíò wípé, Àwa kò fẹ́ Bíbélì mọ́—Olúwa bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè sọ̀rọ̀—Òun yíò ṣe ìdájọ́ fún ayé láti inú àwọn ìwé èyí tí a ó kọ. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ọ̀pọ̀ ni yíò wà—ni ọ̀jọ́ nã nígbàtí èmi yíò tẹ̀ síwájú láti ṣe iṣẹ́ ìyanu lãrín wọn, kí èmi lè rántí àwọn májẹ̀mú mi èyí tí mo ti ṣe sí àwọn ọmọ ènìyàn, kí èmi lè tún mú ọwọ́ mi ní ìgbà kejì láti gba àwọn ènìyàn mi padà, tí wọ́n jẹ́ ará ilé Isráẹ́lì; Àti pẹ̀lú, kí èmi lè rántí àwọn ìlérí èyí tí mo ti ṣe sí ọ, Nífáì, àti pẹ̀lú sí bàbá rẹ, pé èmi yíò rántí irú-ọmọ rẹ; àti pé àwọn ọ̀rọ̀ irú ọmọ rẹ yíò tẹ̀ jáde lọ láti ẹnu mi sí irú ọmọ rẹ; àwọn ọ̀rọ̀ mi yíò sì kọ jáde títí dé ikangun ayé, fún ọ̀págun sí àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n jẹ́ ará ilé Isráẹ́lì; Àti nítorí àwọn ọ̀rọ̀ mi yíò kọ jáde—ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Kèfèrí yíò wípé: Bíbélì kan! Bíbélì kan! Àwa ti ní Bíbélì kan, kò sì lè sí Bíbélì èyíkeyí mọ́. Ṣùgbọ́n báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: A! àwọn aṣiwèrè, wọn yíò ní Bíbélì kan; yíò sì jáde wá láti ọ̀dọ̀ àwọn Jũ, àwọn ènìyàn mi àtijọ́ tí mo bá dá májẹ̀mú. Wọ́n ha dúpẹ́ fún àwọn Jũ fún Bíbélì èyí tí wọ́n gbà láti ọ̀dọ̀ wọn? Bẹ̃ni, kíni àwọn Kèfèrí rò? Njẹ́ wọn rántí àwọn lãlã, àti ìṣẹ́, àti ìrora àwọn Jũ, àti ãpọn wọn sí mi, ní mímú ìgbàlà jáde wá sí àwọn Kèfèrí bí? A! ẹ̀yin Kèfèrí, ẹ̀yin ha ti rántí àwọn Jũ, àwọn ènìyàn mi àtijọ́ tí mo bá dá májẹ̀mú bí? Rárá; ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fi wọ́n bú, tí ẹ sì ti kórìra wọn ẹ kò sì tí ì wá láti mú wọn padà. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, èmi yíò dá gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí padà sórí ara yín; nítorí èmi Olúwa kò ì tí ì gbàgbé àwọn ènìyàn mi. Ẹ̀yin aṣiwèrè, tí yíò wípé: Bíbélì kan, àwa ti ní Bíbélì kan, àwa kò fẹ́ Bíbélì si i. Ẹ̀yin ha ti rí Bíbélì gbà bíkòṣe nípasẹ̀ àwọn Jũ? Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé orílẹ̀-èdè wà ju ọ̀kan lọ? Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé èmi, Olúwa Ọlọ́run yín, ti dá gbogbo ènìyàn, àti pe èmi rántí àwọn wọnnì tí ó wà lórí erékùṣù òkun; àti pe mo jọba ní òkè ọ̀run àti nísàlẹ̀ ilẹ̀; èmi sì mú ọ̀rọ̀ mi jáde wá sí àwọn ọmọ ènìyàn, bẹ̃ni, àní sí órí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé? Èéṣe tí ẹ̀yin fi nkùn, nítorí tí ẹ̀yin yíò gba ọ̀rọ̀ mí sĩ? Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé ẹ̀rí orílẹ̀-èdè méjì jẹ́ ẹ̀rí sí yín pé èmi ni Ọlọ́run, pé mo rántí orílẹ̀-èdè kan bí ti òmíràn? Nítorí-èyi, mo sọ àwọn ọ̀rọ̀ kannã sí orílẹ̀-èdè kan bí ti òmíràn. Nígbàtí àwọn orílẹ̀-èdè méjẽjì yíò sì péjọ ẹ̀rí àwọn orílẹ̀-èdè méjẽjì yíò péjọ pẹ̀lú. Èmi sì ṣe èyí kí èmi lè fihàn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ pé èmi jẹ́ ọ̀kannã ní àná, ní òní, àti títí lae; àti pé èmi sọ àwọn ọ̀rọ̀ mi jáde gẹ́gẹ́bí inú dídùn tèmi. Nítorí tí mo sì ti sọ ọ̀rọ̀ kan kò yẹ́ kí ẹ̀ ṣebí pé èmi kò lè sọ òmíràn; nítorí iṣẹ́ mi kò ì tí ì parí síbẹ̀; bẹ̃ni kì yíò rí bẹ̃ títí òpin ènìyàn,bẹ̃ni kì í sì ṣe láti ìgbà nã lọ àti títí láé. Nítorí-èyi, nítorí tí ẹ̀yin ní Bíbélì kan kò yẹ kí ẹ̀yin ṣebí pé ó ní gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ mi nínú; bẹ̃ni kò yẹ kí ẹ ṣebí pé nkò ti mú kí á kọ sí i. Nítorí mo pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn, àti ní ìlà-oòrùn àti ní ìwọ̀-oòrùn, àti ní àríwà, àti ní gũsù, àti ní àwọn erékùṣù òkun, pé wọn yíò kọ àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo sọ sí wọn; nítorí láti inú àwọn ìwé èyí tí a ó kọ ni èmi yíò ṣe ìdájọ́ fún ayé, olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ wọn, gẹ́gẹ́bí àwọn èyí tí a kọ. Nítorí kíyèsĩ i, èmi yíò bá àwọn Jũ sọ̀rọ̀ wọn yíò sì kọ ọ́; èmi yíò sì bá àwọn ará Nífáì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn yíò sì kọ ọ́; èmi yíò sì bá àwọn ẹ̀yà ará ilé Isráẹ́lì míràn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú, tí mo ti tọ́ kúrò lọ wọn yíò sì kọ ọ́; èmi yíò sì bá gbogbo orílẹ̀-èdè àgbáyé sọ̀rọ̀ wọn yíò sì kọ ọ́. Yíò sì ṣe tí àwọn Jũ yíò ní àwọn ọ̀rọ̀ àwọn ará Nífáì, àwọn ará Nífáì nã yíò sì ní àwọn ọ̀rọ̀ àwọn Jũ; àwọn ará Nífáì àti àwọn Jũ yíò sì ní àwọn ọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀yà Isráẹ́lì tí ó ti sọnù; àwọn ẹ̀yà Isráẹ́lì tí ó ti sọnù yíò sì ní àwọn ọ̀rọ̀ àwọn ará Nífáì àti àwọn Jũ. Yíò sì ṣe tí a ó kó àwọn ènìyàn mi, tí nṣe ti ará ilé Isráẹ́lì, jọ sílẹ̀ sí àwọn ilẹ̀ ìní wọn; a ó sì kó ọ̀rọ̀ mi jọ ní ọ̀kan pẹ̀lú. Èmi yíò sì fi hàn sí àwọn tí nbá ọ̀rọ̀ mi àti àwọn ènìyàn mi jà, tí nṣe ti ará ilé Isráẹ́lì, pé èmi ni Ọlọ́run, àti pé èmi dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ábráhámù pé èmi yíò rántí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé. 30 A ó ka àwọn Kèfèrí tí a yí lọ́kàn padà pẹ̀lú àwọn ènìyàn májẹ̀mú—Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ará Lámánì àti àwọn Jũ yíò gba ọ̀rọ̀ nã gbọ́ wọn yíò sì di wíwuni—A ó mú Isráẹ́lì padà sípò a ó sì pa ènìyàn búburú run. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi yíò sọ̀rọ̀ sí yín; nítorí èmi, Nífáì, kì yíò yọ̣́da kí ẹ̀yin kí ó ṣebí pé ẹ̀yin jẹ́ olódodo ju bí àwọn Kèfèrí yíò ṣe jẹ́. Nítorí kíyèsĩ i, àfi bí ẹ̀yin yíò bá pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ gbogbo yín yíò parun bẹ̃gẹ́gẹ́; àti nítorí ti àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí a ti sọ kò yẹ kí ẹ̀yin ṣèbí pé a ti pa àwọn Kèfèrí run pátápátá. Nítorí kíyèsĩ i, mo wí fún yín pé ọ̀pọ̀ iye àwọn Kèfèrí tí ó bá ronúpìwàdà ni ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa; ọ̀pọ̀ iye àwọn Jũ tí kò bá sì ronúpìwàdà ni a ó ké kúrò; nítorí Olúwa kò dá májẹ̀mú pẹ̀lú ẹnikẹ́ni bíkòṣe pẹ̀lú àwọn tí ó bá ronúpìwàdà tí ó sì gbàgbọ́ nínú Ọmọ rẹ̀, ẹni tí i ṣe Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì. Àti nísisìyí, èmi yíò sọ-tẹ́lẹ̀ díẹ̀ sĩ nípa àwọn Jũ àti àwọn Kèfèrí. Nítorí lẹ́hìn tí ìwé èyí tí mo ti sọrọ nípa rẹ̀ yíò jáde wá, tí a ó sì kọ sí àwọn Kèfèrí, tí a ó sì tún fi èdídì dì í sókè sí Olúwa, ọ̀pọ̀ ni yíò wà tí yíò gba àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí a kọ gbọ́; wọn yíò sì gbé wọn jáde sí ìyókù irú-ọmọ wa. Nígbànã sì ni ìyòkù irú-ọmọ wa yíò mọ̀ nípa wa, bí a ṣe jádewá láti Jerúsálẹ́mù, àti pé àwọn jẹ́ àtẹ̀lé àwọn Jũ. Ìhìn-rere Jésù Krístì ni a ó sì kéde lãrín wọn; nítorí-èyi, a ó mú wọn padà sípò sí ìmọ̀ àwọn bàbá wọn, àti pẹ̀lú sí ìmọ̀ Jésù Krístì, èyí tí a ní lãrín àwọn bàbá wọn. Nígbànã sì ni wọn yíò yọ̀; nítorí wọn yíò mọ̀ pé ó jẹ́ ìbùkún fún wọn láti ọwọ́ Ọlọ́run; ìpẹ́ òkùnkùn wọn yíò sì bẹ̀rẹ̀sí jábọ́ kúrò ní ojú wọn; ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran kì yíò sì kọjá kúrò lãrín wọn, àfi tí wọn bá jẹ́ ènìyàn tí ó mọ́ tí ó sì wuni. Yíò sì ṣe tí àwọn Jũ èyí tí a túká yíò bẹ̀rẹ̀sí gbàgbọ́ nínú Krístì pẹ̀lú; wọn yíò sì bẹ̀rẹ̀sí péjọ sí ori ilẹ̀ ayé; ọ̀pọ̀ iye àwọn tí yíò sì gbàgbọ́ nínú Krístì yíò di ènìyàn wíwuni pẹ̀lú. Yíò sì ṣe tí Olúwa Ọlọ́run yíò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ lãrín gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn, láti mú mímú padà sípò àwọn ènìyàn rẹ̀ wá sí órí ayé. Àti pẹ̀lú òdodo ni Olúwa Ọlọ́run yíò ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà, yíò sì báni wí pẹ̀lú ìṣòtítọ́ fún àwọn ọlọ́kàn tútù ayé. Òun yíò sì lu ayé pẹ̀lú ọ̀gọ ẹnu rẹ̀; àti pẹ̀lú ẽmí àwọn ètè rẹ̀ ni yíò sì pa àwọn ènìyàn búburú. Nítorí àkókò nã nbọ̀wá kíákíá tí Olúwa Ọlọ́run yíò mú ìpín nlá kan ṣẹ lãrín àwọn ènìyàn, àwọn ènìyàn búburú ni òun yíò sì parun; òun yíò sì dá àwọn ènìyàn rẹ̀ sí, bẹ̃ni, àní bí ó ṣe pé òun yíò pa àwọn ènìyàn búburú run nípasẹ̀ iná. Òdodo yíò sì jẹ́ àmùrè ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti ìṣòtítọ́ àmùrè inú rẹ̀. Àti nígbànã ni ìkọ́kò yíò gbé pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùtàn; ẹkùn yíò sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlũ, àti ọmọ kìnìún, àti ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa, papọ̀; ọmọ kékeré kan yíò sì má dà wọ́n. Àti màlũ àti béárì yíò sì ma jẹ; àwọn ọmọ wọn yíò dùbúlẹ̀ pọ̀; kìnìún yíò sì jẹ koríko bí màlũ. Ọmọ ẹnu-ọmú yíò sì ṣiré ní ihò pãmọ́lè, ọmọ tí a já lẹ́nu ọmú yíò sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí ihò gùnte. Wọn kì yíò panilára bẹ̃ni wọn kì yíò panirun ní gbogbo òkè mímọ́ mi; nítorí ayé yíò kún fún ìmọ̀ Olúwa gẹ́gẹ́bí omi ti bò ojú òkun. Nítorí-èyi, àwọn ohun gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sọ di mímọ̀; bẹ̃ni, àwọn ohun gbogbo ni a ó sọ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn. Kò sí nkan tí ó jẹ́ ohun ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní fi hàn; kò sí iṣẹ́ òkùnkùn tí a kò ní fi han ní ìmọ́lẹ̀; kò sì sí nkan tí a fi èdídì dì lórí ilẹ̀ ayé tí a kò ní tú sílẹ̀. Nítorí-èyi, gbogbo àwọn ohun tí a ti fihàn sí àwọn ọmọ ènìyàn ni a ó fihàn ní ọjọ́ nã; Sátánì kì yíò sì ní agbára lórí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn mọ́, fún ìgbà pípẹ́. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo fi òpin sí àwọn ọ̀rọ̀ sísọ mi. 31 Nífáì sọ ìdí rẹ̀ tí a fi rì Krístì bọmi—Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ tẹ̀lé Krístì, kí á rì wọn bọmi, kí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́, kí wọ́n sì forítì í dé òpin kí a lè gbà wọ́n là—Ìrònúpìwàdà àti ìrìbọmi ni ẹnu-ọ̀nà sí ojú-ọ̀nà híhá àti tọ́ró—Ìyè àìnípẹ̀kun nwá fúnàwọn tí ó bá pa àwọn òfin mọ́ lẹ́hìn ìrìbọmi. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí èmi, Nífáì, fi òpin sí ísọ-tẹ́lẹ̀ mi sí yín, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́. Èmi kò sì lè kọ̀wé àfi àwọn ohun díẹ̀, èyí tí mo mọ̀ pé dájúdájú kò lè ṣàìṣẹ; bẹ̃ni èmi kò le kọ̀we àfi díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ arákùnrin mi Jákọ́bù. Nítorí-èyi, àwọn ohun èyí tí mo ti kọ tẹ́ mi lọ́rùn, àfi ti àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí èmi gbọdọ̀ sọ nípa ẹ̀kọ́ Krístì; nítorí-èyi, èmi yíò sọ̀rọ̀ fún yín ni kedere, gẹ́gẹ́bí ti kíkedere sísọ-tẹ́lẹ̀ mi. Nítorí ọkàn mi yọ̀ ní kíkedere; nítorí irú ọ̀nà báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run gbà nṣiṣẹ́ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn. Nítorí Olúwa Ọlọ́run fúnni ní ìmọ́lẹ̀ fún òye; nítorí tí o sọ̀rọ̀ sí ènìyàn gẹ́gẹ́bí èdè wọn, fún oye wọn. Nítorí-èyi, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí pé èmi ti sọ̀rọ̀ fún yín nípa wòlĩ nì èyí tí Olúwa fihàn sí mi, tí yíò rì Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run bọmi, tí yíò kó àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ. Àti nísisìyí, bí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, òun tí ó jẹ́ mímọ́, bá rĩ pé ó tọ́ kí á rì òun bọmi nípa ti omi, láti mú gbogbo òdodo ṣẹ, A! njẹ́, báwo ni o ṣe tọ́ fun wa to, tí a jẹ́ aláìmọ́, láti ṣe ìrìbọmi, bẹ̃ni, àní nípa ti omi! Àti nísisìyí, èmi yíò bí yín, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, nínú kíni Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run ti mú gbogbo òdodo ṣẹ ní mímúu ṣe ìrìbọmi nípati omi? Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé ó jẹ́ mímọ́ bí? Ṣùgbọ́n l’áìṣírò ó jẹ́ mímọ́, ó fihàn sí àwọn ọmọ ènìyàn pé, nípa ti ara òun rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Bàbá, ó sì jẹ́rĩ sí Bàbá pé òun yíò ní ígbọ́ran sí i ní pípa àwọn òfin rẹ̀ mọ́. Nítorí-èyi, lẹ́hìn tí a rì bọmi pẹ̀lú omi Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀kalẹ̀ sí órí rẹ̀ ní ìṣe ti àdàbà. Àti ẹ̀wẹ̀, ó fihàn sí àwọn ọmọ ènìyàn híhá ọ̀nà nã, àti títọ́ró ẹnu-ọ̀nà nã, nípasẹ̀ èyí tí wọn yíò wọlé, níwọ̀n bí òun ti fi àpẹrẹ lélẹ̀ níwájú wọn. Ó sì wí fún àwọn ọmọ ènìyàn: Ẹ̀yin ẹ máa tọ̀ mí lẹ́hìn. Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, àwá ha lè tọ Jésù lẹ́hìn bíkòṣe pe àwa yíò ní ìfẹ́ láti pa àwọn òfin Baba mọ́? Baba nã sì wípé: Ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà, kí á sì rì yín bọmi ní orúkọ Àyànfẹ́ Ọmọ mi. Àti pẹ̀lú, ohùn ti Ọmọ nã wá sọ́dọ̀ mi, ó nwí pé: Ẹni nã tí a bá rìbọmi ní orúkọ mi, sí òun ni Baba yíò fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún, bí tí èmi; nítorí-èyi, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́hìn, kí ẹ sì ṣe àwọn ohun tí ẹ ti rí mi tí mo ṣe. Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo mọ̀ pé bí ẹ̀yin yíò bá tọ Ọmọ nã lẹ́hìn, pẹ̀lú èrò ọkàn kíkún, láìṣe ìwà àgàbàgebè àti láìsí ẹ̀tàn níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdí tí o dájú, tí ẹ̀ nronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, tí ẹ̀ njẹ́rĩ sí Baba pé ẹ̀yin ní ìfẹ́ láti gbé orúkọ Krístì lé órí, nípasẹ̀ ìrìbọmi—bẹ̃ni, nípasẹ̀ títọ Olúwa yín àti Olùgbàlà yín lẹ́hìn sọ̀kalẹ̀ sínú omi, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kíyèsĩ i, nígbànã ni ẹ̀yin yíò rí Ẹ̀mí Mímọ́ gba; bẹ̃ni, nígbànã ni ìrìbọmi ti iná àti ti Ẹ̀mí Mímọ́ yíò wá; nígbànã sì ni ẹ̀yin lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ahọ́n àwọn ángẹ́lì, tí ẹ sì lè pariwo ìyìn sí Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì. Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, báyĩ ni ohùn Ọmọ na a wá sí ọ̀dọ̀ mi, ó nwí pé: Lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, tí ẹ sì jẹ́rĩ sí Baba pé ẹ̀yin ní ìfẹ́ láti pa àwọn òfin mi mọ́, nípasẹ̀ ìrìbọmi ti omi, tí ẹ sì ti gba ìrìbọmi ti iná àti ti Ẹ̀mí Mímọ́, tí ẹ sì lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ahọ́n titun, bẹ̃ni, àní pẹ̀lú ahọ́n àwọn ángẹ́lì, àti lẹ́hìn èyí tí ẹ bá sẹ́ mi, ìbá ti sànjù fún yín kí ẹ̀yin má ti mọ̀ mí. Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Baba, tí ó nwípé: Bẹ̃ni, àwọn ọ̀rọ̀ Àyànfẹ́ mi jẹ́ òtítọ́ àti òdodo. Ẹni tí ó bá forítì í títí dé òpin, òun nã ni a ó gbàlà. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo mọ̀ nípa èyí pé bíkòṣepé ènìyàn bá forítì í dé òpín, ní títẹ̀lé àpẹrẹ ti Ọmọ Ọlọ́run alãyè, a kò lè gbà á là. Nítorí-èyi, ẹ ṣe àwọn ohun èyí tí mo ti sọ fún yín tí mo ti rí tí Olúwa yín àti Olùràpadà yín yíò ṣe; nítorí, fún ìdí èyí ni a ṣe fi wọ́n hàn sí mi, kí ẹ̀yin lè mọ́ ẹnu ọ̀nà nípasẹ̀ èyí tí ẹ̀yin yíò bá wọlé. Nítorí ẹnu ọ̀nà nípasẹ̀ èyí tí ẹ̀yin yíò bá wọlé ni ìrònúpìwàdà àti ìrìbọmi nípasẹ̀ omi; nígbànã sì ni ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín nípasẹ̀ iná àti nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ nbọ̀wá. Nígbànã sì ni ẹ̀yin wà ní ọ̀nà híhá àti tọ́ró yí èyí tí ó ṣe amọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun; bẹ̃ni, ẹ̀yin ti wọlé nípasẹ̀ ẹnu ọ̀nà, ẹ̀yin ti ṣe gẹ́gẹ́bí àwọn òfin ti Baba àti Ọmọ; ẹ̀yin sì ti gba Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí o jẹ́rĩ Baba àti Ọmọ, sí mímú ìlérí èyí tí ó ti ṣe ṣẹ, pé bí ẹ̀yin bá wọlé nípasẹ̀ ọ̀nà nã ẹ̀yin yíò rí gbà. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, lẹ́hìn ti ẹ̀yin bá ti bọ́ sí ọ̀nà híhá àti tọ́ró yí, ẹ̀mi yíò bèrè bóyá a ti ṣe gbogbo nkan? Kíyèsĩ, mo wí fún yin, Rárá; nítorí ẹ̀yin kò ti wá jìnà tó èyí bíkòṣe nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Krístì pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí kò mì nínú rẹ̀, tí ẹ ngbẹ́kẹ̀lé gbogbo àṣepé rẹ̀ pátápátá, ẹni tí ó jẹ́ alágbára láti gbàlà. Nítorí-èyi, ẹ̀yin kò lè sai tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì, kí ẹ ní ìrètí dídán, àti ìfẹ́ ti Ọlọ́run àti ti gbogbo àwọn ènìyàn. Nítorí-èyi, bí ẹ̀yin yíò bá tẹ̀síwájú, tí ẹ̀ nṣe àpéjẹ lórí ọ̀rọ̀ Krístì, tí ẹ sì forítì í dé òpin, kíyèsĩ i, báyĩ í ni Baba wí: Ẹ̀yin yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun. Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èyí ni ọ̀nà nã; kò sì sí ọ̀nà míràn tàbí orúkọ tí a fi fún ni lábẹ́ ọ̀run nípa èyí tí a lè fi gba ènìyàn là ní ìjọba Ọlọ́run. Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, èyí ni ẹ̀kọ́ ti Krístì, àti ẹ̀kọ́ ọ̀kanṣoṣo àti òtítọ́ ti Baba, àti ti Ọmọ, àti ti Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí ó jẹ́ Ọlọ́run kan, àìnípẹ̀kun òpin. Àmín. 32 Àwọn angẹ́lì sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́—Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ gbàdúrà kí wọ́n sì rí ìmọ̀ gbà fún àwọn tìkarãwọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo ṣèbí ẹ̀yin wádĩ díẹ̀ ní ọkàn yín nípa ohun èyí tí ẹ̀yin yíò ṣe lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti wọlé nípasẹ̀ ọ̀nànã. Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ, ẽṣe tí ẹ̀yin fi nwádĩ àwọn ohun wọ̀nyí ní ọkàn yín? Ẹ̀yin kò ha rántí pé mo wí fún yín pé lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti gba Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ahọ́n àwọn angẹ́lì? Àti nísisìyí, báwo ni ẹ̀yin ṣe lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ahọ́n àwọn angẹ́lì bíkòṣe tí ó jẹ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́? Àwọn angẹ́lì nsọ̀rọ̀ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́; nítorí-èyi, wọ́n nsọ àwọn ọ̀rọ̀ Krístì. Nítoríèyi, mo wí fún yín, ẹ ṣe àpéjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì; nítorí kíyèsĩ i, àwọn ọ̀rọ̀ Krístì yíò sọ fún yín gbogbo àwọn ohun èyí tí ó yẹ kí ẹ ṣe. Nítorí-èyi, nísisìyí lẹ́hìn tí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, bí òye wọn kò bá yé e yín yíò jẹ́ nítorí pé ẹ̀yin kò bèrè, bẹ̃ni ẹ̀yin kò kànkùn; nítorí-èyi, a kò mú yín wá sínú ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò lè ṣe aiparun nínú òkùnkùn. Nítorí kíyèsĩ i, mo tun wí fún yín pé bí ẹ̀yin yíò bá wọlé nípasẹ̀ ọ̀nà nã, kí ẹ sì gba Ẹ̀mí Mímọ́, òun yíò fi gbogbo àwọn ohun hàn sí yin èyí tí ó yẹ kí ẹ sẹ. Kíyèsĩ i, èyí ni ẹ̀kọ́ Krístì, kì yíò sì sí ẹ̀kọ́ sí i tí a ó fi fún ni títí di lẹ́hìn tí òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí yín nínú ara. Nígbàtí òun yíò sì fi ara rẹ̀ hàn sí yín nínú ara, àwọn ohun èyí tí òun yíò sọ fún yín ni ẹ̀yin yíò ṣọ́ láti ṣe. Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kò lè sọ̀rọ̀ sí i; Ẹ̀mí dá ọ̀rọ̀ sísọ mi dúró, a sì fi mí sílẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ nítorí ti àìgbàgbọ́, àti ìwà búburú, àti àìmọ̀, àti ọrùn líle àwọn ènìyàn; nítorí wọn kì yíò wádĩ ìmọ̀, tàbí kí ìmọ̀ nlá yé wọn, nígbàtí a fi fún wọn ní kerekere, àní ní kerekere bí ọ̀rọ̀ ṣe lè wà. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo wòye pé ẹ̀yin nwádĩ síbẹ̀síbẹ̀ ní ọkàn yín; ó sì mú mi kẹ́dùn pé èmi gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun yí. Nítorí bí ẹ̀yin bá fetísílẹ̀ sí Ẹ̀mí èyí tí nkọ́ ènìyàn láti gbàdúrà, ẹ̀yin yíò mọ̀ pé ẹ̀yin gbọdọ̀ gbàdúrà; nítorí ẹ̀mí ibi kì í kọ́ ènìyàn láti gbàdúrà, ṣùgbọ́n ó nkọ́ ọ pé òun kò gbọdọ̀ gbadura. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, mo wí fún yín pé ẹ̀yin gbọdọ̀ gbàdúrà nígbà-gbogbo, kí ẹ má sì ṣe ṣãrẹ̀; pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun sí Olúwa àfi níṣãjú bí ẹ̀yin yíò bá gbàdúrà sí Baba ní orúkọ Krístì, kí òun kí ó lè ya ìṣe yín sí mímọ́ sí yín, kí ìṣe yín lè wà fún àlãfíà ọkàn yín. 33 Àwọn ọ̀rọ̀ Nífáì jẹ́ òtítọ́—Wọ́n jẹ́rĩ Krístì—Àwọn wọnnì t í wọ́n gbàgbọ́ nínú Krístì yíò gba àwọn ọ̀rọ̀ Nífáì gbọ́, Tí yíò dúró bí ẹ̀rí níwájú irin ìdájọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kò lè kọ gbogbo àwọn ohun tí a kọ́ni lãrín àwọn ènìyàn mi; bẹ̃ni èmi kò jẹ́ alágbára ní kíkọ̀wé, bí ti sísọ̀rọ̀; nítorí nígbàtí ènìyàn bá sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́, agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ngbé e sí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ọ̀pọ̀ ni ó wà tí wọ́n sé ọkàn wọn le sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí kò ní ãyè nínú wọn; nítorí-èyi, wọ́n sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohunèyí tí a kọ nù wọ́n sì kà wọ́n sí gẹ́gẹ́bí ohun asán. Ṣugbọn èmi, Nífáì, ti kọ ohun tí mo ti kọ, mo sì kà á sí gẹ́gẹ́bí iye nlá, àti pãpã fún àwọn ènìyàn mi. Nítorí mo gbàdúrà léraléra fún wọn nígbà ọ̀sán, ojú mi sì bù omi rin irọ̀rí mi nígbà òru, nítorí ti wọn; mo sì kígbe sí Ọlọ́run mi ní ìgbàgbọ́, mo sì mọ̀ pé òun yíò gbọ́ igbe mi. Mo sì mọ̀ pé Olúwa Ọlọ́run yíò ya àwọn àdúrà mi sí mímọ́ fún ànfàní àwọn ènìyàn mi. Àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo sì ti kọ ní àìmókun ni a ó mú lágbára sí wọn; nítorí ó yí wọn lọ́kàn padà láti ṣe rere; ó mú kí wọ́n mọ̀ nípa àwọn baba wọn; ó sì sọ̀rọ̀ nípa Jésù, ó sì yí wọn lọ́kàn padà láti gbàgbọ́ nínú rẹ̀, àti láti forítì í dé òpin, èyí tí ó jẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun. Ó sì sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà líle sí ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́bí ti kíkedere ti òtítọ́; nítorí-èyi, ẹnikẹ́ni kì yíò bínú sí àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo ti kọ àfi tí òun yíò bá jẹ́ ti ẹ̀mí èṣù. Mo ṣògo nínú kíkedere; mo ṣògo nínú òtítọ́; mo ṣògo nínú Jésù mi, nítorí òun ti ra ọkàn mi padà kúrò nínú ọ̀run àpãdì. Mo ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ fún àwọn ènìyàn mi, àti ìgbàgbọ́ nlá nínú Krístì pé èmi yíò bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn pàdé láìlábàwọ́n ní ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀. Mo ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ fún àwọn Jũ—mo wípé Jũ, nítorí mo rò wọn láti ibi ti èmi ti wá. Mo ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ fún àwọn Kèfèrí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, kò sí ẹnìkan nínú àwọn wọ̀nyí tí mo lè ní ìrètí fún àfi tí wọn yíò bá ṣe ìlàjà sí Krístì, kí wọ́n sì wọlé sínú ẹnu ọ̀nà tọ́ró nã, kí wọ́n sì rìn ní ọ̀nà híhá èyí tí ó tọ́ sí ìyè, kí wọ́n sì dúró títí ní ọ̀nà nã dé òpin ọjọ́ ìdánwò. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, àti Jũ pẹ̀lú, àti gbogbo ẹ̀yin ikangun ayé, ẹ fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kí ẹ sì gbàgbọ́ nínú Krístì; bí ẹ̀yin kò bá sì gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ẹ gbàgbọ́ nínú Krístì. Bí ẹ̀yin yíò bá sì gbàgbọ́ nínú Krístì ẹ̀yin yíò gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nítorí wọ́n jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, ó sì ti fi wọ́n fún mi; wọ́n sì kọ́ gbogbo ènìyàn pé kí wọn ṣe rere. Bí wọn kò bá sì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, ẹ ṣe ìdájọ́—nítorí Krístì yíò fi hàn sí yín, pẹ̀lú agbára àti ògó nlá, pé wọ́n jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ òun, ní ọjọ́ ìkẹhìn; ẹ̀yin àti èmi yíò sì dúró lójúkojú níwájú irin-ilé-ẹjọ́ rẹ̀; ẹ̀yin yíò sì mọ̀ pé a ti pàṣẹ fún mi nípa rẹ̀ láti kọ àwọn ohun wọ̀nyí, l’áìṣírò àìlágbára mi. Mo sì gbàdúrà sí Baba ní orúkọ Krístì pé ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa, bí kò bá jẹ́ gbogbo wa, le rí igbala ní ìjọba rẹ̀ ní ọjọ́ nlá àti ìkẹhìn nì. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, gbogbo àwọn wọnnì tí ó jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì, àti gbogbo ẹ̀yin ikangun ayé, mo sọ̀rọ̀ sí yín bí ohùn ti ẹni tí ó nké láti inú eruku wá: Ó dìgbà míràn títí ọjọ́ nlá nì yíò dé. Ẹ̀yin tí kì yíò bá sì pín nínú ọ́re Ọlọ́run, kí ẹ sì bọ̀wọ̀ fún àwọn ọ̀rọ̀ àwọn Jũ, àti àwọn ọ̀rọ̀ mi pẹ̀lú, àti àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí yíò jáde wá láti ẹnu Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, kíyèsĩ i, mo ṣe ó dìgbàsí yín títí ayé, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yíò dá yín lẹ́bi ní ọjọ́ ìkẹhìn. Nítorí ohun ti mo bá fi èdídì dì ní ayé, ni a ó mú wá dojúkọ yín ní ìjòkó ìdájọ́; nítorí báyĩ ni Olúwa pàṣẹ fún mi, èmi sì gbọdọ̀ gbọ́ran. Amin. 1 Jákọ́bù àti Jósẹ́fù wá ọ̀nà láti yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà láti gbàgbọ́ nínú Krístì kí nwọ́n sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́—Nífáì kú—Ìwà búburú gbilẹ̀ l’ãrín àwọn ará Nífáì. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa. NÌTORÍ kíyèsĩ, ó sì ṣe pé ãdọ́ta ọdún ó lé mãrún ti kọjá láti ìgbà tí Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù; nígbànã, Nífáì fún èmi, Jákọ́bù ní òfin kan nípa àwọn àwọn àwo kékeré nnì, lórí èyítí a gbẹ́ àwọn nkan wọ̀nyí lé. Ó sì fún èmi, Jákọ́bù, ní òfin kan pé kí èmi kí ó kọ ọ́ lé orí àwọn àwo wọ̀nyí díẹ̀ nínú àwọn nkan tí mo kãkún pé ó jẹ́ iyebíye jùlọ; pé kí èmi máṣe fi ọwọ́ kàn, àfi ní ṣòkí, nípa ìtàn àwọn ènìyàn yĩ tí à npè ní àwọn ènìyàn Nífáì. Nítorítí ó sọ̀ wípé kí a fín ìtàn àwọn ènìyàn rẹ̀ sí orí àwọn àwo rẹ̀ míràn, pé kí èmi kí ó sì pa àwọn àwo wọ̀nyí mọ́ kí èmi kí ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ èso mi, láti ìran dé ìran. Tí ìwãsù tí ó jẹ́ mímọ́, tàbí ìfihàn tí ó tóbi, tàbí ìsọtẹ́lẹ̀ bá wà, pé kí èmi kí ó fín àwọn èyí tí ó ṣe kókó nínú wọn sí orí àwo wọ̀nyí, kí èmi kí ó sì kọ nípa wọn bí ó ti pọ̀ tó, nítorí ti Krístì, àti fún ànfãní àwọn ènìyàn wa. Nítorípé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti àníyàn jọjọ, a ti fihàn wá nítòọ́tọ́ nípa àwọn ènìyàn wa, ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ sí nwọn. A sì ní àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfihàn pẹ̀lú àti ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ púpọ̀; nítoríèyi, a mọ̀ nípa Krístì àti ìjọba rẹ̀ èyítí nbọ̀wá. Nítorí-èyi a ṣiṣẹ́ taratara ní ãrín àwọn ènìyàn wa, kí àwa kí ó lè yí wọn l’ọ́kàn padà láti wá sọ́dọ̀ Krístì, kí wọ́n sì ní ìpín nínú ire Ọlọ́run, kí nwọ́n wọ inú ìsinmi rẹ̀, bí bẹ̃kọ́ ní ọ̀nà kọnà òun ó búra nínú ìbínú rẹ̀ pé kí wọ́n má wọlé, gẹ́gẹ́bí ìmúnibínú ti ìgbà ìdánniwò nígbàtí àwọn ọmọ Ísráélì wà ní aginjù. Nítorí-èyi, àwa nfẹ́, nípa ọ́re ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa lè yí ọkàn gbogbo ènìyàn padà kí nwọn máṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, láti pẽ ní ìjà sí ìbínú, ṣùgbọ́n kí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ nínú Krístì, kí wọ́n sì gba ikú rẹ̀ rò, ki nwọn ro ìjìyà rẹ̀ lórí àgbélèbú, àti kí wọ́n faradà ìtìjú ayé; nítorí-èyi, èmi Jákọ́bù, pinnu láti mú òfin arákùnrin mi Nífáì ṣẹ. Nísisìyí Nífáì bẹ̀rẹ̀sí di arúgbó, ó sì ríi pé òun yíò kú láìpẹ́; nítorí-èyi ó ṣe ìfòróró yàn fún ọkùnrin kan láti jẹ́ ọba àti alãkóso lórí àwọn ènìyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́bí ìjọba àwọn ọba. Àwọn ènìyàn nã nítorítí nwọ́n fẹ́ràn Nífáì lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorítí òun ti jẹ́ alãbò nlá fún wọn, nítorítí ó fi agbára lo idà Lábánì ní ìdãbò fún wọn àti nítorítí ó ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ fún àlãfíà nwọn— Nítorí-èyi, àwọn ènìyàn nã ní ìfẹ́ láti jẹ́ orúkọ rẹ̀ sí ìrántí. Ẹnití yíò bá sì jọba rọ́pò rẹ̀ ni àwọn ènìyàn pè ní Nífáì èkejì, Nífáì ẹ̀kẹ́ta, àti bẹ̃bẹ̃ lọ, nípa ìjọba àwọn ọba nã; báyĩ sì ni àwọn ènìyàn nã pè nwọ́n, èyíkẽyí orúkọ tí wọn ìbã fẹ́ láti jẹ́. Ó sì ṣe tí Nífáì kú. Ní báyĩ àwọn ènìyàn tí nwọn kĩ ṣe ará Lámánì, jẹ́ ará Nífáì; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a pè wọ́n ní ará Nífáì, ará Jákọ́bù, ará Jósẹ́fù, ará Sórámù, ará Lámánì, ará Lémúẹ́lì, àti ará Íṣmáélì. Ṣùgbọ́n èmi, Jákọ́bù kò ní ṣe ìyàtọ̀ sí wọn nípasẹ̀ orúkọ wọ̀nyí, ṣùgbọ́n èmi yíò pè wọ́n ní ará Lámánì èyítí ó lépa láti pa àwọn ènìyàn Nífáì run, àti àwọn tí wọ́n bá sì bá Nífáì ṣe ọ̀rẹ́ ni èmi yíò pè ní ará Nífáì, tàbí àwọn ènìyàn Nífáì gẹ́gẹ́bí ìṣe àwọn ìjọba àwọn ọba. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ará Nífáì, ní ábẹ́ ìjọba ọba èkejì, bẹ̀rẹ̀sí sé aya nwọn le, nwọ́n sì nhu àwọn ìwà búburú, gẹ́gẹ́bí Dáfídì ti ìgbà nnì tí ó nfẹ́ láti ní ìyàwó àti àlè púpọ̀, àti Sólómọ́nì pẹ̀lú, ọmọkùnrin rẹ̀. Bẹ̃ni, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà àti fàdákà pẹ̀lú, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sĩ gbé ojú sókè nínú ìwà ìgbéraga. Nítorí-èyi èmi, Jákọ́bù, fún wọn ní àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí mo ṣe kọ́ wọ́n nínú tẹ́mpìlì, nítorítí èmi ti kọ́kọ́ gba iṣẹ́ mi lọ́dọ̀ Olúwa. Nítorí, èmi, Jákọ́bù, pẹ̀lú arákùnrin mi Jósẹ́fù, ni a ti yà sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́bí àlùfã àti olùkọ́ni fún àwọn ènìyàn yĩ, láti ọwọ́ Nífáì. Àwa sì ṣe ìmútóbi ipò tí a pè wá sí, wa sí Olúwa, ní siṣe ojuse wa, ki a si dáhùnsí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí sori wa tí àwa kò bá kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọkàn-tọkàn; nítorí-èyi, nípa ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú agbára wa, ẹ̀jẹ̀ wọn kò ní wá sí ára aṣọ wa; bíbẹ̃kọ́, ẹ̀jẹ̀ wọn yíò wá sí ára aṣọ wa, a kò sì ní wà ní mímọ́ ní ọjọ́ ìkẹhìn. 2 Jákọ́bù ṣe ìkọ̀sílẹ̀ ọrọ̀, ìgbéraga, àti àìpa-ara-ẹni-mọ́—àwọn ènìyàn lè lépa ọrọ̀ fún ìrànlọ́wọ́ àwọn arákùnrin nwọn—Jákọ́bù fi ẹnu ẹ̀tẹ́ bá fífẹ́ aya púpọ̀ tí kò ní àṣẹ nínú—Olúwa ní ìyọ́nú sí wíwà-ní-mímọ́ àwọn obìnrin. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jákọ́bù, arákùnrinNífáì, bá àwọn ará Nífáì sọ, lẹ́hìn ikú Nífáì: Nísisìyí, ẹ̀nyin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi, Jákọ́bù, gẹ́gẹ́bí ipò tí mo wà ní ìhà Ọlọ́run, láti ṣe ìmútóbi ipò tí a pè mi sí mi pẹ̀lú ìwà ìfarabalẹ̀, àti pẹ̀lú pé kí èmi kí ó lè wẹ ẹ̀wù mi mọ́ ní ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ nyín, èmi wá sí tẹ́mpìlì ní òní kí èmi kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún nyín. Ẹ̀yin fúnra yín sì mọ̀ pé títí di ìsisìyí pé mo ti ṣe ãpọn nípa ìpè mi; ṣùgbọ́n ní òní yĩ, ọkàn mi wúwo púpọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àníyàn àti ãjò fún wíwà ní àlãfíà ẹ̀mí nyin ju ti àtẹ̀hìnwá. Nítorí kíyèsĩ, ní báyĩ, ẹ̀nyin ti ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Olúwa, èyítí mo ti fi fún un nyín. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ẹ fetísílẹ̀ sí mi, kí ẹ sì mọ̀ pé nípa ìrànlọ́wọ́ ẹni-alágbára-jùlọ, Ẹlẹ́dã Ọ̀run òun aiyé èmi lè sọ fún nyín nípa èrò ọkàn nyín, bí ẹ̀yin ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀sẹ̀ èyítí ó jẹ́ ìríra jùlọ níwájú mi, bẹ̃ni, àti tí ó jẹ́ ìríra jùlọ níwájú Ọlọ́run. Bẹ̃ni, ó jẹ́ ohun ẹ̀dùn fún ọkàn mi, ó sì jẹ́ kí èmi kí ó súnrakì pẹ̀lú ìtìjú ní iwájú Ẹlẹ́da mi, pé èmi gbọ́dọ̀ j’ẹ̀rí síi nyín nípa búburú ọkàn nyín. Àti pẹ̀lú ó sì jẹ́ ohun ẹ̀dùn fún mi pé mo níláti fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa nyín, níwájú àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ nyín, tí ọ̀pọ̀ èrò ọkàn púpọ̀ nínú wọn jẹ́ ọ̀dọ́ àti wíwà-ní-mímọ́ àti ẹlẹgẹ́ níwájú Ọlọ́run, èyítí ó jẹ́ ohun ìdùnnú fún Ọlọ́run; Ó sì jẹ́ ohun tí èmi rò pé wọ́n wá sí ìhín láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èyítí ó tuni nínú, bẹ̃ni, ọ̀rọ̀ tí í ṣe ìwòsàn fún ọkàn tí ó gbọgbẹ́. Nítorí-èyi, ó jẹ́ ohun ìnira fún ọkàn mi pé mo níláti mú u ní dandan, nítorí òfin tí ó múná èyítí èmi ti gbà láti ọ́wọ́ Ọlọ́run, láti rọ̀ yín níti ìwà búburú nyin, èyítí o dá kun ìrora àwọn tí a ti dá lóró, kàkà kí ẹ̀nyin ìbá tù wọ́n nínú, kí ẹ sì wo awọn ọgbẹ́ wọn san; àti àwọn tí ọkàn nwọn kò ì tĩ gb’ọgbẹ́, kàkà kí ẹ̀nyin ó fi ọ̀rọ̀ ìtùnú Ọlọ́run bọ́ nwọn, ẹ̀nyin fi ọ̀kọ̀ gún wọn ní ọkàn tí ẹ sì ṣá iyè inú ẹlẹgẹ́ wọn lọ́gbẹ́. Ṣùgbọ́n, l’áìṣírò títóbi iṣẹ́ nã, èmi níláti ṣe gẹ́gẹ́bí àwọn òfin tí ó múná ti Ọlọ́run, kí èmi kí ó sì sọ fún nyín nípa ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra yín, níwájú ẹnití ọkàn rẹ mọ́, tí ó sì gbọgbẹ́, àti lábẹ́ ìwárìrì ojú Ọlọ́run Olódùmarè tí ó rí ohun gbogbo. Nítorí-èyi, mo níláti sọ òtítọ́ fún nyín nípa kedere ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí kíyèsi, bí èmi ṣe ṣe ìwádĩ lọ́dọ̀ Olúwa, bẹ̃ni ọ̀rọ̀ nã tọ̀ mi wa, tí ó sọ wípé: Jákọ́bù, dìde lọ sínú tẹ́mpìlì ní ọ̀la, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ nã èyítí èmi yíò fi fún ọ fún àwọn ènìyàn yí. Àti nísisìyí kiyesì, ẹ̀nyin arákùnrin mi, èyí ni ọ̀rọ̀ ná tí èmi sọ fún nyín, wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nyín ti bẹ̀rẹ̀sí ṣe àférí wúrà, àti fún fàdákà, àti fún oríṣiríṣi àwọn irin aìpò olówó iyebíye, nínú ilẹ̀ yìi, èyítí í ṣe ilẹ̀ ìlérí fún ẹ̀nyin àti àwọn irú ọmọ nyin, èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú rẹ. Àti pẹ̀lú pé òjò ìbùkún sì ti rọ̀ lé nyín lórí lọ́pọ̀lọpọ̀, tí ẹ̀yin sì ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; àti nítorípé àwọn míràn nínú nyín ti gbà lọ́pọ̀lọpọ̀ ju àwọn arákùnrin nyín lọ, a gbé yín sókè nínúìgbéraga ọkàn nyín, ẹ̀ nṣe ọkàn líle àti orí kunkun nítorí aṣọ olówó iyebíye yín, ẹ sì npẹ̀gàn àwọn arákùnrin nyín nítorítí ẹ̀nyin rò wípé ẹ dára jú nwọ́n lọ. Àti nísisìyí, ẹ̀nyin arákùnrin mi, njẹ́ ẹ rò wípé Ọlọ́run dá nyín láre nínú nkan yĩ? Kíyèsĩ, mo wí fún nyín, rara. Ṣùgbọ́n ó dá nyin lẹ́bi, tí ẹ̀nyin bá sì tẹramọ́ ṣíṣe ohun wọ̀nyí, ìdájọ́ rẹ níláti tọ́ nyín wà kánkán. A! òun ìbá sì fi hàn nyín pé òun lè gún yín, àti pé, pẹ̀lú wíwo ìṣẹ́jú akàn pẹ̀lú ojú rẹ̀, òun leè lu nyín bolẹ̀ mọ́ eruku. A! òun ìbá sí gbọ̀n yín nù kúrò nínú àìṣedẽdé àti ohun ìríra yĩ. Àti pé, A! ẹ̀nyin ìbá sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìpaláṣẹ rẹ, kí ẹ má sì jẹ́ kí ìgbéraga ọkàn nyín yí pa ẹ̀mí nyín run! Ẹ rò nípa àwọn arákùnrin nyín gẹ́gẹ́bí ara yín. Kí ẹ sì fifúnni nínú ohun ìní nyín, kí nwọ́n lè ní ọrọ̀ bí ẹ̀yin. Ṣugbọ́n kí ẹ̀nyin tó lépa ọrọ̀, ẹ lépa ìjọba Ọlọ́run. Àti lẹ́hìn tí ẹ̀nyin bá ti gba ìrètí nínú Krístì, ẹ̀nyin yíò gba ọrọ̀, tí ẹ bá lépa nwọn; ẹ̀nyin yíò sì lépa wọn fún èrò láti ṣe rere—láti wọ aṣọ fún ẹnití ó wà ní áìbò, àti áti bọ́ ẹnití ebi npa, àti láti tú ẹnití ó wà ní ìgbèkùn sílẹ̀, àti láti ṣe ìtọ́jú aláìsàn àti ẹnití ìyà njẹ. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi ti sọ̀rọ̀ fún nyín nípa ìgbéraga; àti ẹ̀nyin tí ẹ ti fi ìyà jẹ aládũgbò nyín, tí ẹ sì ṣe inúnibíni síi nítorípé ẹ̀nyin gbéraga ni ọ́kàn nyín, nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run ti fún nyín, kíni ẹ̀nyin sọ nípa rẹ? Ẹ̀yin kò ha rò wípé àwọn nkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìríra sí ẹnití ó da gbogbo ẹlẹ́ran-ara? Àti pé ẹ̀dá kan níye lórí ní ojú rẹ̀ gẹ́gẹ́bí èkejì. Àti pé erùpẹ̀ ni gbogbo ẹlẹ́ran ara; àti fún ara rẹ̀ kan nã ni ó ṣe dá nwọn, pé kí wọn lè pa awọn òfin òun mọ́, kí wọ́n sì máa yìn òun títí láé. Àti nísisìyí, èmi dẹ́kun bíbá nyín sọ̀rọ̀ nípa ìgbéraga yĩ. Bí kò bá sí ṣe pé mo níláti sọ̀rọ̀ fún nyín nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ga ju t’àtẹ̀hìnwá, ọkàn mi kì bá yọ̀ púpọ̀ nítorí yín. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ mí lọ́rùn nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ nyín èyítí ó ga ju ti àtẹ̀hìnwá. Sì kíyèsĩ, báyĩ ni Olúwa wí: Àwọn ènìyàn wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí gbilẹ̀ nínú àìṣedẽdé; ìwé-mímọ́ kò yé wọn, nítorítí nwọ́n nífẹ́ láti dá ara wọn láre nínú ìwà àgbèrè, nítorí àwọn nkan tí a kọ nípa Dáfídì, àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀. Kíyèsĩ, Dáfídì àti Sólómọ́nì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ aya pẹ̀lú àlè nítọ́tọ́, èyítí ó jẹ́ ohun ìríra níwájú mi, ni Olúwa wí. Nítorí-èyi, báyĩ ni Olúwa wí, èmi ti darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, nípa agbára apá mi, kí èmi lè gbe ẹ̀ka olódodo kan dìde sí èmi láti inú èso ti ìhà Jósẹ́fù. Nítorí-èyi, èmi Olúwa Ọlọ́run kò ní gbà kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe bí àwọn ará ìgbà nnì. Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ gbọ́ mi, kí ẹ sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Olúwa: Bẹ̃ni ẹnì kan nínú nyín kò gbọ́dọ̀ ní ju aya kan; kò sì gbọ́dọ̀ ní àlè kankan; Nítorípé èmi, Olúwa Ọlọ́run, dunnú sí wíwà-ní-mímọ́ àwọnobìnrin. Àwọn ìwà àgbèrè sì jẹ́ ohun-ìríra níwájú mi; báyĩ ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wi. Nítorí-èyi, àwọn ènìyàn yĩ yíò pa àwọn òfin mi mọ́, ní Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, l’áìjẹ́ bẹ̃, a ó fi ilẹ̀ nã bú nítorí nwọn. Nítorípé bí èmi bá fẹ́, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, gbé irú-ọmọ dìde fún mi, èmi yíò paṣẹ fún àwọn ènìyàn mi; bíbẹ̃kọ́ nwọn yíò fetísílẹ̀ sí àwọn ohun wọ̀nyí. Nítorí kíyèsĩ, èmi, Olúwa, ti rí ìrora-ọkàn nã, mo sì ti gbọ́ ìbinújẹ́ àwọn ọmọbìnrin dáradára àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, bẹ̃ni, àti ní gbogbo ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi, nítorí ìwà búburú àti ìwà ìríra àwọn ọkọ wọn. Àti pé, èmi kò ní gbà, ni Olúwa àwọnỌmọ-ogun wí, pé kí igbe àwọn ọmọbìnrin dáradára àwọn ènìyàn yĩ, tí mo ti sin jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, gòkè tọ̀ mí wá, ní ìkọlù àwọn okùnrin àwọn ènìyàn mi, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wi. Nítorítí wọn kò ní mú àwọn ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi jáde lọ sí ìgbèkùn nítorí ìwàpẹ̀lẹ́ wọn, láìjẹ́bẹ́ẹ̀ èmi yíò bẹ̀ wọ́n wò pẹ̀lú ègún kíkan, àní sí ìparun; nítorítí wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè, gẹ́gẹ́bí àwọn ará ìgbãnì, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wi. Àti nísisìyí kìyésĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀yin mọ̀ pé a fi àwọn òfin wọ̀nyí fún bàbá wa, Léhì; nítorí-èyi, ẹ̀yin ti mọ̀ wọ́n láti àtẹ̀hìnwá; ẹ̀yin sì ti dé ibi ìdálẹ́bi tí ó ga; nítorítí ẹ̀yin ti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí tí kò yẹ kí ẹ̀yin ṣe. Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti ṣe àìṣedẽdé èyítí ó ga jù ti àwọn Lámánì, àwọn arákùnrin wa, lọ. Ẹ̀yin mú ìrètí àti ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn ìyàwó yín oníwàpẹ̀lẹ́ kíó ṣákì, ẹ̀yin sì ti pàdánù ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ yín nínú nyín, nítorí àpẹrẹ ìwà búburú yín níwájú wọn; ẹkún wọn sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ ní ìdojúkọ nyín. Àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó múná, èyítí ó wá ní ìdojúkọ yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn ni ó kú nínú ipò ìrora ọgbẹ́ jíjìn. 3 Àwọn ọlọ́kàn-mímọ́ gba ọ̀rọ̀ ìdùnnú Ọlọ́run-òdodo àwọn ará Lámánì tayọ ti àwọn ará Nífáì—Jákọ́bù kìlọ̀ nípa àgbèrè ìfẹ́kúfẹ́ ara, àti ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èmi, Jákọ́bù, yíò sọ̀rọ̀ sí ẹ̀yin ọlọ́kàn-mímọ́. Gbé ojú rẹ sókè sí Ọlọ́run pẹ̀lú àìyẹra ọkàn, sì gbàdúrà síi pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàgbọ́, òun yíò sì tù ọ́ nínú ní inu àwọn ìṣòro rẹ, òun yíò sì ṣe alágbàwí fún ọ, yíò sì rán aiṣegbe sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn tí nwọ́n wá ìparun rẹ̀. A!, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọlọ́kànmímọ́, ẹ gbé orí yín sókè, kí ẹ sì gba ọ̀rọ̀ ìdùnnú Ọlọ́run, kí ẹ sì ṣe àpèjẹ lórí ìfẹ́ rẹ̀; nítorítí ẹ̀yin le ṣe eleyĩ, tí ẹ bá ní ìdúró ṣinṣin ọkàn, títí láé. Ṣùgbọ́n, ègbé, ègbé, ni fún ẹ̀nyin tí ẹ kò jẹ́ ọlọ́kàn-mímọ́, tí ẹ jẹ́ elẽrí loni níwájú Ọlọ́run; nítorípé, bíkòṣepé ẹ̀yin ronúpìwàdà,ìfibú ni ilẹ̀ nã nítorí yín; àti àwọn ará Lámánì, tí wọ́n kò jẹ́ elẽrí bĩ tiyín, bíótilẹ̀ríbẹ̃, tí a fi bú pẹ̀lú ègún kíkan, wọn yíò kọlũ yín sí ìparun. Ìgbà nã sì dé kánkán, bíkòṣepé ẹ̀yin bá ronúpìwàdà, wọn yíò jogún ilẹ̀ ìní yín, Olúwa yíò sì sin àwọn olódodo jáde kúrò ní ãrín yín. Kíyèsĩ, àwọn àrá Lámánì arákùnrin yín, tí ẹ̀yin korira nítorí ìwà ẽrí wọn àti ègún tí ó ti wá sí ara nwọn, jẹ́ olododo jù yín lọ; nítorítí wọn kò tĩ gbàgbé òfin Olúwa, èyítí a fún àwọn bàbá wa—pé wọn kò gbọ́dọ̀ ní ju ìyàwó kan lọ, àti pé nwọn kò gbọ́dọ̀ ní àlè, àti pẹ̀lú pé a kò gbọ́dọ̀ rí ìwà àgbèrè ní ãrín wọn. Àti nísisìyí, òfin yĩ ni wọ́n gbiyanju láti pa mọ́; nítorí-èyi, nítorí àkíyèsí yĩ, nípa pípa òfin yĩ mọ́, Olúwa Ọlọ́run kò ní pa wọ́n rẹ́, ṣùgbọ́n yíò ṣe ãnú fún wọn; ní ọjọ́ kan, wọ́n yíò di ẹni ìbùkún. Kíyèsĩ, àwọn ọkọ wọn fẹ́ràn àwọn ìyàwó wọn, àwọn ìyàwó nwọn sì fẹ́ràn àwọn ọkọ wọn; àti àwọn ọkọ wọn àti àwọn ìyàwó fẹ́ràn àwọn ọmọ wọn; àti pé àìgbàgbọ́ wọn àti ikorira wọ́n sí yín sì jẹ́ nítorí àìṣedẽdé àwọn bàbá wọn; nítorí-èyi, báwo ni ẹ̀yin ṣe dára jù wọ́n lọtó, lójú Ẹlẹ́dã yín tí ó tóbi? A! ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀rù nbá mí pé, bí kò ṣe pé ẹ̀nyin bá ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ yín, awọ ara wọn yíò funfun ju tiyín lọ, nígbàtí a ó mù yin wá pẹ̀lú wọn síwájú ìtẹ́ Ọlọ́run. Nítorí-èyi, àṣẹ kan ni mo fi fún un yín, èyítí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pé kí ẹ̀nyin máṣe kẹ́gàn wọn mọ́ nítorí dúdú awọ ara wọn; bẹ̃ni ẹ̀nyin kì yíò sì kẹ́gàn wọn nítorí ìwà ẽrí wọn; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yíò rántí ìwà ẽrí yín, kí ẹ sì rántí pé ìwà ẽrí nwọn wá nítorí àwọn bàbá wọn. Nítorí-èyi, ẹ̀yin yíò rántí àwọn ọmọ yín, bí ẹ̀yin ṣe ti bà nwọn lọ́kàn jẹ nítorí àpẹrẹ tí ẹ fi lélẹ̀ níwájú wọn; àti pẹ̀lú, kí ẹ rántí pé ẹ̀yin lè ti ipasẹ̀ ìwà ẽrí yín mú ìparun bá àwọn ọmọ yín, a o sì di ẹ̀ṣẹ̀ wọn lée yín lórí ní ọjọ ìkẹhìn. A! ẹ̀yin ará mi, ẹ fi etí sílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi; ẹ ta ọkàn yín jí; ẹ gbọn ara yín nù, kí ẹ̀yin kí ó lè tají kúrò nínú ọ́gbé ikú; kí ẹ sì tú ara yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìrora ọ̀run àpãdì, kí ẹ̀yin kí ó má bà di àwọn ángẹ́lì ti èṣù, tí a ó jù sínú adágún iná àti imí ọjọ́ nã, èyítí í ṣe ikú èkejì. Àti nísisìyí èmi, Jákọ́bù, sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan síwájú sĩ fún àwọn ará Nífáì, ní kíkìlọ̀ fún nwọn nípa ìwà àgbèrè àti ifẹkufẹ-ara, àti irúkírú ẹṣẹ, mo sì sọ fún wọn nípa èrè àwọn ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí. Àti pé, idá kan nínú ọgọrun ìṣe àwọn ènìyàn wọ̀nyí, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ sí di púpọ̀ bayĩ, ni a kò lè kọ sorí àwọn àwo wọ̀nyí; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣe wọn ni a kọ sórí àwọn àwo tí ó tóbi ju àwọn tí a sọ wọ̀nyí, àti àwọn ogun wọn, àti asọ̀ wọn, àti ìjọba àwọn ọba wọn. Àwọn àwo wọ̀nyí ni a pè ní àwo Jákọ́bù, a sì ṣe wọ́n nípasẹ̀ ọwọ́ Nífáì. Èmi sì mú sísọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá sí òpin. 4 Gbogbo àwọn wòlĩ sin Bàbá ní orúkọ Krístì—Yíyọ̀da Ísãkì fún ìrúbọ, èyítí Ábráhámù ṣe, jẹ́ àwòkọ́ṣe ti Ọlọ́run àti ti Ọmọ Bíbí rẹ̀ Nìkanṣoṣo—Ènìyàn níláti bá Ọlọ́run làjà nípasẹ̀ Ètùtù nã—Àwọn Jũ yíò kọ okúta ìpìlẹ̀ nã sílẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí kíyèsĩ, ó sì ṣe tí èmi, Jákọ́bù, lẹ́hìn tí mo ti jíṣẹ́ púpọ̀ fún àwọn ènìyàn mi nínú ọ̀rọ̀ sísọ, (nkò sì lè kọ bí kò ṣe díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ mi, nítorí ìṣòro fifin àwọn ọ̀rọ̀ wa sí ara àwọn àwo) àwa sì mọ̀ wípé àwọn nkan tí a kọ sórí àwọn àwo níláti wà síbẹ̀; Ṣùgbọ́n, ohunkóhun tí àwa bá kọ lé orí ohunkóhun, yàtọ̀ sí orí àwọn àwo níláti parun, kí wọn ó sì parẹ́; ṣùgbọ́n àwa lè kọ ọ̀rọ̀ díẹ̀ lé orí àwọn àwo, èyítí yíò fún àwọn ọmọ wa, àti àwọn arákùnrin wa àyànfẹ́, ní ìmọ̀ díẹ̀ nípa wa, tàbí nípa àwọn bàbá wọn— Nísisìyí, nínú èyí ni àwa nyọ̀; àwa sì nṣiṣẹ́ tọkàn-tọkàn láti fín àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sórí ara àwọn àwo, ní ìrètí pé àwọn arákùnrin wa àyànfẹ́ àti àwọn ọmọ wa yíò gbà wọ́n pẹ̀lú ọkàn ìdúpẹ́, kí wọ́n sì wo wọn, kí wọn bá lè kọ́ ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ayọ̀, kĩ ṣe pẹ̀lú ìrora-ọkàn bẹ̃ sì ni kĩ ṣe pẹ̀lú ìkẹgàn, nípa àwọn òbí wọn àkọ́kọ́. Nítorí ìdí èyí ni àwa ṣe kọ àwọn nkan wọ̀nyí, kí wọn kí ó lè mọ̀ pé àwa mọ̀ nípa Krístì, àti pé à ní ìrètí ògo rẹ̀ ní ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgọ̣́rún ọdún ṣãjú bíbọ̀ rẹ̀; àti pé àwa nìkan kọ́ ní a ní ìrètí ògo rẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ tí wọ́n ti wà ṣãjú wa. Kíyèsĩ, wọ́n gbàgbọ́ nínú Krístì, wọ́n sin Bàbá ní orúkọ rẹ̀, àwa nã sin Bàbá ní orúkọ rẹ̀. Àti nítorí ìdí èyí ni àwa ṣe pa òfin Mósè mọ́, nítorítí ó tọ́ka ọkàn wa sĩ; àti nítorí ìdí èyí ni ó ṣe wà ní ìyàsímímọ́ fún wa fún ìwà òdodo, pãpã gẹ́gẹ́bí a ṣe kãkún fún Ábráhámù nínú aginjù, pé kí ó ṣe ìgbọràn sí àwọn òfin Ọlọ́run nípa yíyọ̀da ọmọkùnrin rẹ̀ Ísãkì fún ìrúbọ, èyítí ó jẹ́ àwòkọ́ṣe ti Ọlọ́run àti ti Ọmọ Bíbí rẹ̀ Kanṣoṣo. Nítorí-èyi, àwa ṣe àwárí àwọn wòlĩ, àwa sì nì ìfihàn tí ó pọ̀, àti ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀; nígbàtí àwa sì ti gba ẹ̀rí wọ̀nyí, a rí ìrètí gbà, ìgbàgbọ́ wa sì wa láìmì, tóbẹ̃ gẹ́ tí a fi lè pàṣẹ lọ́ótọ́ ní orúkọ Jésù, fún àwọn igi, tàbí àwọn òkè gíga, tàbí àwọn ìrusókè omi òkun, tí nwọn sì gbọ́. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa Ọlọ́run nfi àìlera wa hàn wá kí àwa kí ó lè mọ̀ pé nípa ọ́re-ọ̀fẹ́ rẹ̀, àti ìrẹra-ẹni-sílẹ̀ títóbi nítorí àwọn ọmọ ènìyàn, ni àwa fi lè ní agbára láti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí. Kíyèsĩ, títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ Olúwa. Awamaridi sì ni ìjìnlẹ̀ ìṣe rẹ̀; kòsí ṣeéṣe fún ènìyàn láti mọ gbogbo ọ̀nà rẹ. Kò sì sí ẹni nã tí ó mọ ọ̀nà rẹ, àfi bí a bá fi hàn an; nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ máṣe fi ẹnu àbùkù bá àwọn ìfihàn Ọlọ́run. Nítorí kíyèsĩ, nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ènìyàn fi wá sí orí ilẹ̀ ayé, èyítí a dá nípa agbára ọ̀rọ̀rẹ̀. Nítorí-èyi, bí Ọlọ́run bá lè sọ̀rọ̀, tí ayé sì wà, kí ó sì sọ̀rọ̀, tí a sì dá ènìyàn, A! njẹ́, báwo ni kò ṣe ní lè pàṣẹ fún ayé, tàbí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé nã, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti inúdídùn rẹ̀? Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin, ẹ má ṣe lépa láti gba Olúwa ní ìmọ̀ràn, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó gba ìmọ̀ràn láti ọwọ́ rẹ̀. Nítori kíyèsĩ, ẹ̀yin tikara yín mọ̀ wípé ó nfún ni ní ìmọ̀ràn nínú ọgbọn, àti nínú àìṣègbè, àti nínú ọ̀pọ̀ ãnú, lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin àyànfẹ́, ẹ bá làjà, nípasẹ̀ ètùtù Krístì, Ọmọ Bíbí rẹ̀ Kanṣoṣo, ẹ̀yin sì lè rí àjĩnde gbà gẹ́gẹ́bí agbára àjínde tí ó wà nínú Krístì, kí a sì fi yín sí iwájú Ọlọ́run, gẹ́gẹ́bí àkọ́bí Krístì, nípa ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ sì ti gba ìrètí ogo dáradára nínú rẹ̀, kí ó tó fi ara rẹ̀ hàn nínú ẹran ara. Àti nísisìyí, ẹ̀nyin àyànfẹ́, ẹ máṣe jẹ́ kí ó yà yín lẹ́nu wípé èmi nsọ àwọn nkan wọ̀nyí fún yín; ẽṣe tí àwa kò sọ̀rọ̀ nípa ètùtù Krístì, kí àwa kí ó sì ní ìmọ̀ pípé nípa rẹ̀, gẹ́gẹ́bí àwa yíò ṣe ní ìmọ̀ nípa àjinde àti ayé èyí tí ó nbọ̀? Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹnití ó bá nsọ àsọtẹ́lẹ̀, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn; nítorítí Ẹ̀mí nsọ òtítọ́, kĩ sĩ purọ́. Nítorí-èyi, ó nsọ̀rọ̀ nípa ohun gbogbo bí wọ́n ṣe rí gan an, àti nípa ohun gbogbo bí wọ́n yíò ṣe rí gan an; nítorí-èyi, a fi àwọn nkan wọ̀nyí hàn wá ní kedere, fún ìgbàlà ọkàn wa. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwa nìkan kọ́ ni à nṣe ẹlẹ́rĩ nínú àwọn nkan wọ̀nyí; nítorítí Ọlọ́run pãpã sọ wọ́n fún àwọn wòlĩ àtẹ̀hìnwá pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ, àwọn Jũ jẹ́ ọlọrun líle ènìyàn; wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ ti o ṣe kedere, wọ́n sì pa àwọn wòlĩ, wọ́n sì ṣe àfẹ́rí àwọn nkan tí kò lè yé wọ́n. Nítorí-èyi, nítorí ìfọ́jú wọn, ìfọ́jú èyítí o bá nwọn nípa àwojúmọ́, wọ́n níláti ṣubú; nítorípé Ọlọ́run ti mú ìṣe-kedere rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì fún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan tí kò lè yé wọn, nítorí wọ́n fẹ́ẹ bẹ̃. Àti nítorítí wọ́n fẹ́ bẹ̃, Ọlọ́run ṣe é, kí wọ́n lè kọsẹ̀. Àti nísisìyí, èmi, Jákọ́bù ni à darí nípa Ẹ̀mí láti sọtẹ́lẹ̀; nítorítí mo wòye nípa ìṣe Ẹ̀mí tí ó wà nínú mi, wípé nípa ìkọsẹ̀ àwọn Jũ wọn yíò kọ okuta nã sílẹ̀ orí èyítí wọ́n kì bá kọle sí, kí wọ́n sì ní ìpìlẹ̀ tí ó wà láìléwu. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, gẹ́gẹ́bí àwọn ìwé-mímọ́, okuta yí yíò di nla, yíò sì jẹ́ èyí tí ó kẹ́hìn, àti ìpìlẹ̀ kanṣoṣo tí ó dájú, orí èyí tí àwọn Jũ yíò lè kọ́ ilé lé. Àti nísisìyí, ẹ̀nyin àyànfẹ́ mi, báwo ni o ṣe lè ṣeéṣe pé àwọn wọ̀nyí, lẹ́hìn tí wọ́n ti kọ ìpìlẹ̀ nã tí ó dájú sílẹ̀, wọn yíò ha lè kọ́ ilé lée lórí, tí yíò sì jẹ́ òpómúléró fún nwọn bí? Kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi yíò fi ìmọ̀ yí yé yín; bí èmi, ní ọ̀nàkọnà, kò bá yẹ̀ kúrò ní ìdúróṣinṣin mi nínú Ẹ̀mí, kí èmi sì kọsẹ̀ nítorí ìkó-ọkàn-sókè lórí nyín. 5 Jákọ́bù sọ ọ̀rọ̀ ti Sénọ́sì sọ nípa ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ti igi ólífì tí a tọ́jú àti ti asọdigbó. Nwọ́n jẹ́ àfiwé fún Isráẹ́lì àti àwọn Kèfèrí—Fífọ́nka àtiKíkójọpọ̀ Ísráẹ́lì jẹyọ nínú ọ̀rọ̀—A ṣe ìtọ́ka sí àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì àti gbogbo ìdílé Ísráẹ́lì—Àwọn Kèfèrí yíò di àkékún sí ará Ísráẹ́lì—Lẹhinorẹhin, ọgbà-àjàrà nã yíò di jíjó. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa. Kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, ṣé ẹ̀yin kò rántí pé ẹ ti ka àwọn ọ̀rọ̀ ti wòlĩ Sénọ́sì, èyítí o sọ fún ará ilé Ísráẹ́lì, wípé: Fi etí sílẹ̀, A! ẹ̀yin ará ilé Ísráẹ́lì, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, èmi wòlĩ Olúwa. Nítorí ẹ kíyèsĩ, báyĩ ni Olúwa wí, Èmi yíò ṣe àfiwé rẹ, A! ará ilé Isráẹ́lì, pẹ̀lú igi olifi kan tí a tọ́jú ti ọkùnrin kan mu, tí ó sì tọ́jú nínú ọgbà-àjàrà rẹ; tí ó sì dàgbà, tí ó sì gbo, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí díbàjẹ́. Ó sì ṣe, tí olùtọ́jú ọgbà-àjàrà nã jáde lọ, tí ó sì ríi pé igi olifi nã ti bẹ̀rẹ̀ si díbàjẹ́; ó sì wípé: Èmi yíò pa ẹ̀ka rẹ̀, èmi yíò si gbẹ́ ilẹ̀ yĩ ka, èmi yíò sì tọ́jú rẹ̀, pé bóyá yíò rúwé, kò sì ní parun. O sì ṣe, o pa ẹka rẹ, ó sì wa ilẹ̀ yi i ka, ó sì tọ́jú rẹ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì ṣe, lẹ́hìn ọjọ́ púpọ̀, ó bẹ̀rẹ̀sí yọ jáde ní díẹ̀díẹ̀, àwọn ẹ̀ka tí ó jẹ́ ọ̀dọ́; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, òkè orí igi nã bẹ̀rẹ̀ sí parun. Ó sì ṣe, nígbàtí olùtọ́jú ọgbà-àjàrà nã rií, ó sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ wípé: Ó jẹ́ ohun ẹ̀dùn ọkàn fún mi wípé èmi yíò pàdánù igi yĩ; nítorí-èyi, lọ, kí ó ké àwọn ẹ̀yà ẹ̀ka igi ólífì asọdigbó, kí ó sì mú wọn tọ̀ mí wá; àwa yíò sì ké àwọn ẹ̀ka ti wọ́n ti bẹ̀rẹ̀sí rẹ̀ dànù nì kúrò, àwa yíò sì jù wọ́n sínú iná kí wọn kí ó lè jóná. Sì kíyèsĩ, ni Olúwa ọgbà-àjàrà nã wí, èmi yíò mu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iruwe ọ̀dọ́ ẹ̀ka wọ̀nyí kúrò, èmi yíò sì pa ẹ̀ka wọn sí ara igi èyítí o bá wu mi; ko si bá ohunkóhun wí, pé tí ó bá jẹ́ wípé gbòngbò igi yĩ yíò parun, èmi yíò tọ́jú èso rẹ̀ fún ara mi; nítorí-èyi, èmi yíò mú àwọn ọ̀dọ́ ẹ̀ka rírọ wọ̀nyí, èmi yíò si fi wọ́n bọ igi èyítí ó bá wù mi. Mú ẹ̀ka igi ólífì asọdigbó nni, sì fi nwọ́n bọ ara igi míràn dípò èyí tí ó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀; àwọn wọ̀nyí, tí èmi ti ké kúrò ni èmi yíò jù sínú iná tí èmi yíò sì jó wọn, kí wọn kí ó má bã fún gbãyè ọgbà-àjàrà mi. Ó sì ṣe pé ìránṣẹ́ Olúwa ọgbà-àjàrà nã ṣe gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Olúwa ọgbà-àjàrà nã ti pã láṣẹ ó sì fi ẹ̀ka igi ólífì asọdigbó bọ ãrín rẹ̀. Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì jẹ́ kí a gbẹ́ ilẹ̀ yíi ká, kí a sì pẹ̀ka rẹ̀, kí a sì ṣe ìtọ́jú rẹ̀, ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: Ó jẹ́ ìbànújẹ́ fún mi pé èmi yíò pàdánù igi yíi; nítoríèyi, pé bóyá èmi lè tọ́jú gbòngbò rẹ, kí wọ́n má bã parun, kí èmi kí ó ṣe ìtọ́jú wọn fún ara mi, ni èmi ṣe ṣe nkan yĩ. Nítorí-èyi, máa bá tìrẹ lọ; máa ṣọ igi nã, kí o sì tọ́jú rẹ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ mi. Àwọn nkan wọ̀nyí ni èmi yíò gbe ka ibi ìkángun ìhà ìsàlẹ̀ ọgbà-àjàrà mi, ibikíbi èyí tí ó wù mi, kò já mọ́ nkankan sí ọ; èmi sì ṣeé kí èmi lè tọ́jú fún ara mi ẹ̀ka abinibi igi nã; àti pẹ̀lú, kí èmi lè kó èso rẹ̀ pamọ́ di ìgbà míràn sí ara mi; nítorítí ó jẹ́ ohun ẹ̀dùn fún mi láti pàdánù igi yĩ àti èso rẹ̀. Ó sí ṣe wípé Olúwa ọgbààjàrà nã bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ, ó sì fiàwọn ẹ̀ka àbinibí igi ólífì tí a tọ́jú pamọ́ sí ibi ìkángun ìhà ìsàlẹ̀ ọgbà-àjàrà nã, àwọn kan nínú ọ̀kan, àwọn kan nínú òmíràn, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti ìdunnú rẹ. Ó sì ṣe, tí ọjọ́ pípẹ́ kọjá lọ, tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀: Wá, jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ọgbà-àjàrà nã, kí àwa kí ó lè ṣiṣẹ́ nínú ọgbà-àjàrà nã. Ó sì ṣe, tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã, àti ìránṣẹ́ nã pẹ̀lú, sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà-àjàrà nã láti ṣiṣẹ́. Ó sì ṣe, tí ìránṣẹ́ nã sì sọ fún Olúwa rẹ̀, wípé: Kíyèsĩ, wo ibi yĩ; wo igi nã. Ó sì ṣe, tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì wò, ó sì kíyèsí igi nã inú èyítí o ti fi ẹ̀ka igi ólífì asọdigbó bọ̀; ó sì ti hù, ó sì bẹ̀rẹ̀sí nso èso. Ó sì kíyèsĩ pé ó dára; èso rẹ̀ sì dàbĩ ti èso àdánidá. Ó sì wí fún ìránṣẹ́ nã pé: Kíyèsĩ, ẹ̀ka igi asọdigbó nã fa omi mu láti inú egbò rẹ̀ ti inú èyí nã, tóbẹ̃gẹ́ tí egbò nã ti ní agbára púpọ̀; àti nítorí agbára púpọ̀ ti egbò yĩ, ẹ̀ka igi asọdigbó nã ti mú èso igi tí a tọ́jú jáde. Nísisìyí, tí kò bá jẹ́ pé àwa lọ́ si ínú àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí, igi nã kò bá ti parun. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, èmi yíò sì kó èso púpọ̀ pamọ́, èyítí igi nã ti so jáde; èso rẹ̀ ni èmi yíò sì kó pamọ́ di ìgbà míràn, fún ara mi. Ó sì ṣe, tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọ fún ìránṣẹ́ nã wípé: Wá, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sí ìkángun ìsàlẹ̀ ọgbà-àjàrà nã, kí a sì kíyèsĩ, tí àwọn ẹ̀ka àdánidá ti igi nã kò bá tĩ mú èso púpọ̀ jáde bákannã, kí èmi kí ó lè kó àwọn èso nã jọ pamọ́ di ìgbà míràn, fún ara mi. Ó sì ṣe, tí nwọ́n sì lọ sí ibití Olúwa nã ti fi àwọn ẹ̀ka àdánidá igi nã pamọ́ si, ó sì sọ fún ìránṣẹ́ nã wípé: Kíyèsí àwọn wọ̀nyí; ó sì ríi wípé àwọn ti àkọ́kọ́ ti mú èso púpọ̀ jáde wá; ó sì ríi pẹ̀lú pé ó dára. Ó sì sọ fún ìránṣẹ́ nã wípé: Mú nínú àwọn èso ti inú èyí, kí o sì kó wọn jọ pamọ́ di ìgbà míràn, kí èmi kí ó lè tọ́jú nwọn pamọ́ fún ara mi; nítorí kíyèsĩ, ni ó wí, ìgbà pípẹ́ yĩ ni mo ti tọ́jú rẹ, òun si ti so èso púpọ̀ jáde wá. Ó sì ṣe tí ìránṣẹ́ nã sọ fún Olúwa rẹ̀, wípé: Kíni ìdí rẹ̀ tí ìwọ wá sí ibí yĩ láti gbin igi yĩ, tàbí ẹ̀ka igi yĩ? Nítorí kíyèsĩ, ọ̀gangan tí ó ṣá jùlọ nínú gbogbo ilẹ̀ ọgbà-àjàrà rẹ ni. Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọ fún un, pé: Ma gbà mí nímọ̀ràn; èmi mọ̀ pé ilẹ̀ nã ti ṣá; nítorí-èyi ni mo ṣe sọ fún ọ wípé, èmi ti tọ́jú rẹ̀ ní àkókò pípẹ́ yĩ, ìwọ si kíyèsĩ pé ó ti mú èso púpọ̀ jáde wá. Ó sì ṣe tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: Wo ibi yĩ; kíyèsĩ èmi ti gbin ẹ̀ka míràn nínú igi nã; ìwọ sì mọ̀ wípé ilẹ̀ apá ibí yĩ ṣá ju ti àkọ́kọ́ lọ. Ṣùgbọ́n, wo igi nã. Èmi ti tọ́jú rẹ̀ títí di àkokò pípẹ́ yĩ, ó sì ti mú èso púpọ̀ jáde wá; nítorí-èyi, kóo jọ, kí o sì kóo jọ pamọ́ di ìgbà nã, kí èmi kí ó lè tọ́jú nwọn pamọ́ fún ara mi. Ó sì ṣe tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã tún wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: Wo ibí yí, sì kíyèsí ẹ̀ka míràn pẹ̀lú, èyítí mo ti gbìn; kíyèsĩ pé mo ti tọ́jú òun pẹ̀lú, ó sì ti mú èso jáde wá. Ó sì wí fún ìránṣẹ́ nã pé: Wo ibí yĩ, kí o sì kíyèsí ti ìkẹhìn.Kíyèsĩ, èyí ni mo ti gbìn sí orí ilẹ̀ tí ó dára; mo sì ti tọ́jú rẹ̀ títí di àkokò pípẹ́ yíi, díẹ̀ nínú igi nã ni ó sì mú èso tí a tọ́ju jáde, apá kejì igi nã sì mú èso asọdigbó jáde; kíyèsĩ, mo ti tọ́jú igi yĩ bĩ gbogbo àwọn tí ó kù. Ó sì ṣe ti Olúwa-ọgbà àjàrà nã sì sọ fún ìránṣẹ́ nã, wípé: Ke àwọn ẹ̀ka wọnnì kúrò tí kò mu èso rere jáde, kí o sì jù nwọ́n sínú iná. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìránṣẹ́ nã sọ fún un, wípé: Ẹ jẹ́ kí a pa ẹ̀ka rẹ̀, kí a sì wa ilẹ̀ yíi ká, kí a sì tọ́jú rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ síi, pé ó ṣeéṣe kí ó mú èso dáradára jáde wá fún nyín, kí ẹ̀nyin kí ó sì lè kó jọ pọ̀ di ìgbà nã. Ó sì ṣe ti Olúwa ọgbà-àjàrà nã àti ìránṣẹ́ Olúwa ọgbà-àjàrà nã tọ́jú gbogbo èso inú ọgbààjàrà nã. Ó sì ṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ti rékọjá, Olúwa ọgbà-àjàrà nã si sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ wípé: Wá, jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà-àjàrà nã, kí àwa kí ó tún ṣiṣẹ́ nínú ọgbà-àjàrà nã. Nítorí kíyèsĩ, àkokò nã súnmọ́lé, òpin sì dé tán, nítorí-èyi, èmi níláti kó èso jọ papọ̀ di ìgbà nã, fún ara mi. Ó sì ṣe tí Olúwa ọgbààjàrà nã àti ìránṣẹ́ nã lọ sínú ọgbà-àjàrà nã; nwọ́n sì dé ẹ̀bá igi èyítí a ti ké ẹ̀ka àdánidá rẹ̀ kúrò, tí a sì ti mú àwọn ẹ̀ka asọdigbó bọ̀ nínú; sì kíyèsĩ, oríṣiríṣi èso bò igi nã mọ́lẹ̀. Ó sì ṣe tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì tọ́ ní ara èso nã wò, nínú gbogbo onírurú èso ọgbà-àjàrà nã. Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì wípé: Kíyèsĩ, títí di àkokò pípẹ́ yí ni àwa ṣe ìtọ́ju igi yĩ, èmi sì ti kó èso púpọ̀ jọ papọ̀ fún ara mi, di ìgbà nã. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ní ìgbà yí, ó ti mú èso púpọ̀ jáde wá, kò sì sí èyí tí ó dára nínú rẹ. Sì kíyèsĩ, àwọn èso búburú onírurú ni ó wà; kò sì ṣe ànfàní kankan fún mi, l’áìṣírò fún gbogbo lãlã wa; àti nísisìyí jẹ́ ohun ẹ̀dùn fún mi láti pàdánù igi yĩ. Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọ fún ìránṣẹ́ nã wípé: Kíni kí àwa kí ó ṣe sí igi yĩ, kí èmi kí ó leè tun ṣe ìtọ́jú àwọn èso dáradára láti inú rẹ̀ fún ara mi? Ìránṣẹ́ nã sì wí fún Olúwa rẹ̀ pé: Kíyèsĩ, nítorípé ìwọ ti fi ẹ̀ka igi ólífì asọdigbó bọ ãrín igi wọ̀nyí, nwọn sì ti bọ́ àwọn gbòngbò igi nã, wọ́n sì yè, nwọn kò sì parun; nítorí-èyi ni ìwọ ṣe ríi pé nwọ́n ṣì wà ní dídára. Ó sì ṣe tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: Igi nã kò wúlò fún mi, àwọn gbòngbò rẹ ko sì wúlò fún mi pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ wípé èso ibi ni ó nso jáde. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi mọ̀ wípé àwọn gbòngbò rẹ dára, èmi sì ti ṣe ìtọ́jú wọn fún ìwulò ara mi; àti nítorí agbára nwọn ni nwọ́n ṣe mú èso dáradára jáde láti inú àwọn ẹ̀ka tí ó jẹ́ asọdigbó. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ẹ̀ka asọdigbó nã ti gbilẹ̀ nwọ́n ti borí gbòngbò; àti nítorítí ẹ̀ka asọdigbó nã ti gbilẹ̀ borí àwọn gbòngbò rẹ, ó sì ti mú èso búburú púpọ̀ jáde wá; àti nítorítí ó ti mú èso búburú púpọ̀ jùlọ jáde wa, iwọ̀ kíyèsí pé ó bẹ̀rẹ̀ sí parun; yíò sì pọ́n l’áìpẹ́ ọjọ́, kí a lè ju sínú iná, àfi tí àwa bá gbé ìgbésẹ̀ láti lè tọ́jú rẹ̀, kí ó sì yè. Ó sì ṣe ti Olúwa ọgbà-àjàrà nã sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, wípé: Jẹ́ kí a lọ sí àwọn ibi ìhà ìsàlẹ̀ ọgbààjàrà nã, kí a sì ṣe àkíyèsí bóyá àwọn ẹ̀ka àdánidá nã ti mú èso búburú jáde pẹ̀lú. Ó sì ṣe, tí nwọ́n sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn ibi ìhà ìsàlẹ̀ ọgbà-àjàrà nã. Ó sì ṣe, tí nwọ́n ṣe àkíyèsí pé èso ẹ̀ka àdánidá nã pẹ̀lú ti díbàjẹ́; bẹ̃ ni, èkínní àti ìkejì àti ti ìkẹhìn pẹ̀lú; gbogbo nwọn sì ti díbàjẹ́. Èso asọdigbó ti ìkẹhìn si ti borí apá igi nã tí ó mú èso dáradára jáde, tóbẹ̃gẹ́ tí ẹ̀ka igi nã ti rẹ̀ dànù, ó sì ku. Ó sì ṣe, ti Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọkún, ó sì wí fún ìránṣẹ́ nã wípé: Kíni èmi ìbá ti tún ṣe fún ọgbà-àjàrà mi? Kíyèsĩ, mo mọ̀ pé gbogbo èso ọgbà-àjàrà nã, yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí, ni nwọ́n ti díbàjẹ́. Àwọn wọ̀nyí ẹ̀wẹ̀ ti nwọ́n sì ti mú èso dáradára jáde wá ní ìgbà kan rí, sì tún díbàjẹ́ pẹ̀lú; àti nísisìyí gbogbo àwọn igi ọgbà-àjàrà mi kò dára fún ohunkóhun, àfi kí a ké wọn lulẹ̀ kí a sì jù nwọ́n sínú iná. Sì kíyèsí èyí tí ó kẹ́hìn yĩ, èyítí ẹ̀ká rẹ̀ ti rẹ̀ dànù, èmi gbìn ín sí ibi ilẹ̀ tí ó dára; bẹ̃ni, àní èyí tí mo yàn fún ara mi ju gbogbo apá ilẹ̀ yókù nínú ọgbà-àjàrà mi. Ìwọ sì ṣe àkíyèsí pé èmi kée lùlẹ̀ pẹ̀lú, èyítí ó bò apá ibi ilẹ̀ yí mọ́lẹ̀, kí èmi kí ó lè gbin igi yĩ dípò rẹ̀. Ìwọ sì ṣe àkíyèsí pé díẹ̀ nínú igi yĩ mú èso dáradára jáde wa, díẹ̀ nínú rẹ̀ sì mú èso tí asọdigbó jáde; àti nítorítí èmi kò ké àwọn ẹ̀ka rẹ̀, kí a sì jù wọ́n sínú iná, kíyèsĩ, nwọ́n ti bò àwọn ẹ̀ka dáradára mọ́lẹ̀, tó bẹ̃ tí ó ti rẹ̀ dànù. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, l’áìṣírò fún gbogbo ìtọ́jú tí àwa ti ṣe lórí ọgbà-àjàrà mi, àwọn igi rẹ̀ ti díbàjẹ́, ti nwọn kò sì so èso dáradára jáde wá; àwọn wọ̀nyí ni èmi sì ti ní ìrètí nínú láti kó èso nwọn jọ pamọ́ di ìgbà nã, fún ara mi. Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ, nwọn ti dàbí igi ólífì asọdigbó, nwọn kò sì wúlò fún ohunkóhun, bíkòṣe pé kí a ké nwọn lulẹ̀, kí a sì jù nwọ́n sínú iná; ó sì bà mí nínú jẹ́ pé èmi yíò pàdánù nwọn. Ṣùgbọ́n kíni èmi ìbá tún ṣe nínú ọgbà-àjàrà mi? Njẹ́ èmi ṣe ìjáfara bí, ti èmi kò si tọ́jú rẹ? Rárá, èmi ti ṣe ìtọ́jú rẹ̀, mo sì ti wa ilẹ̀ yĩ ka, mo si ti pa ẹ̀ka rẹ kuro, mo ti fi ajílẹ̀ bọ́ọ; èmi sì ti sa gbogbo agbára mi lée lórí, ní ọjọ́ pípẹ́, ìgbẹ̀hìn sì ti dé tán. Ó sì bà mí nínú jẹ́ pé mo níláti gé gbogbo igi inú ọgbà-àjàrà mi lulẹ̀, kí èmi kí ó sì jù nwọ́n sínú iná kí nwọn kí ó lè jóná. Tani ẹni nã tí ó mú kí ọgbà-àjàrà mi díbàjẹ́? Ó sì ṣe, ti ìránṣẹ́ nã sì sọ fún Olúwa rẹ̀, pé: Njẹ́ kĩ ha íṣe gbígbọ́rò ọgbà-àjàrà rẹ—njẹ́ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kò ha ti borí àwọn gbòngbò tí ó dára bí? Nítorípé àwọn ẹ̀ka ti borí àwọn gbòngbò kíyèsĩ nwọ́n dàgbà sókè ju agbára àwọn gbòngbò lọ, nwọ́n sì ngba agbára sí ara wọn. Kíyèsĩ, èmi wípé, njẹ́ kĩ ṣe eleyĩ ni ó fã tí àwọn igi inú ọgbà-àjàrà rẹ ṣe ti díbàjẹ́? Ó sì ṣe, ti Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọ fún ìránṣẹ́ nã pé: Jẹ́ kí àwa kí ó lọ, kí a sì gé àwọn igi inú ọgbà-àjàrà nã lulẹ̀, kí a sìjù nwọ́n sínú iná, kí nwọn kí ó ma ṣe gbilẹ̀ nínú ọgbà-àjàrà mi, nítorítí èmi ti sa gbogbo ipá mi lórí ọgbà-àjàrà yí. Kíni èmi ìbá tún ṣe fún ọgbà-àjàrà mi? Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ, ìránṣẹ́ nã sọ fún Olúwa ọgbà-àjàrà nã pé: Ẹ dáa sí fún ìgbà díẹ̀ síi. Olúwa nã sì wípé: Bẹ̃ni, èmi yíò dáa sí fún ìgbà díẹ̀ síi, nítorítí ó jẹ́ ohun ẹ̀dùn ọkàn fún mi wípé èmi yíò pàdánù àwọn igi inú ọgbà-àjàrà mi. Nítorí-èyi, jẹ́ kí a mú nínú àwọn ẹ̀ka àwọn èyí tí èmi ti gbìn sí ibi ìhà ìsàlẹ̀ ọgbà-àjàrà mi, kí o sì jẹ́ kí a lọ́ àwọn ẹ̀ka nã bọ inú àwọn igi ara èyítí a ti mú wọn jáde wa; kí a sì fa àwọn ẹ̀ka tí wọ́n ti so èso kíkorò yọ kúrò lára igi nã, kí a sì fi àwọn àdánidá ẹ̀ka bọ inú igi nã dípò àwọn wọ̀nyí. Èyí ni èmi yíò sì ṣe kí igi nã má ṣe parun, wípé, bóyá, èmi lè ṣe ìtọ́jú gbòngbò rẹ fún ìwúlò ara mi. Àti kíyèsĩ, àwọn gbòngbò ẹ̀ka àdánidá igi èyí tí mo gbìn sí ibi èyí tí ó wù mí wà lãyè; nítorí-èyi, kí èmi kí ó lè ṣe ìtọ́jú àwọn nã fun ìwúlò ara mi, èmi yíò mú nínú ẹ̀ka igi eleyĩ, èmi yíò sì fi nwọ́n bọ inú wọn. Bẹ̃ni, èmi yíò fi àwọn ẹ̀ka ìdí igi nwọn bọ ãrín wọn, kí èmi kí ó lè dá gbòngbò nwọn pẹ̀lú sí fún èmi tìkalára mi, pé nígbàtí nwọ́n bá ti gbó bóyá nwọn yíò mú èso dáradára jáde wá fún mi, èmi sì le gba ògo nínú èso ọgbà-àjàrà mi síbẹ̀. Ó sì ṣe, ti nwọn sì mú igi àdánidá nã èyítí ó ti di asọdigbó, tí wọ́n sì fi bọ inú àwọn igi àdánidá, èyítí ó ti di asọdigbó bákannã. Nwọ́n sì mú nínú àwọn igi àdánidá tí ó ti di asọdigbó, nwọ́n sì fi nwọ́n bọ inú ìdí igi nwọn. Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì wí fún ìránṣẹ́ nã pé: máṣe gé àwọn ẹ̀ka asọdigbó kúrò lára àwọn igi nã, afi àwọn tí ó korò púpọ̀ jùlọ; ínú nwọn ni ìwọ yíò sì fi bọ gẹ́gẹ́bí èmi ti sọ. Àwa yíò sì tún ṣe ìtọ́jú àwọn igi ọgbà-àjàrà nã, a o sì pa àwọn ẹ̀ka tí ó wà lára rẹ̀; àwa o si ge kúrò lára àwọn igi nã àwọn ẹ̀ka ti nwọn ti díbàjẹ́, tí nwọ́n níláti parun, kí a sì dà wọ́n sínú iná. Èyí ni èmi sì ṣe wípé, bóyá, àwọn gbòngbò rẹ̀ yíò ní agbára nítorí dídára nwọn; àti nítorítí a ti pãrọ̀ àwọn ẹ̀ka nwọn, kí rere lè borí búburú. Àti nítorípé èmi ti tọ́jú àwọn ẹ̀ka àdánidá àti àwọn gbòngbò nwọn, àti wípé èmi ti tún ṣe ìfibọ àwọn ẹ̀ka àdánidá sínú ìdí igi nwọn, tí èmi sì ti tọ́jú àwọn gbòngbò ìdí-igi nwọn, pé, bóyá, àwọn igi inú ọgbà-àjàrà mi yíò tún so èso rere jáde wa; kí èmi sì tún ni ayọ̀ nínú èso inú ọgbààjàrà mi, àti wípé, bóyá èmi lè yọ lọ́pọ̀lọpọ̀ wípé èmi ṣe ìtọ́jú gbòngbò àti ẹ̀ka eso àkọ́kọ́ nã— Nítorí-èyi, lọ, kí o sì pe àwọn ìránṣẹ́, kí àwa lè ṣiṣẹ́ taratara pẹ̀lú agbára wa nínú ọgbà-àjàrà nã, kí àwa kí ó lè tún ọ̀nà nã ṣe, kí èmi tún lè mú èso àdánidá jáde wá, eso adanida èyítí ó dára tí ó sì níye lórí ju gbogbo eso yókù lọ. Nítorí-èyi, jẹ́ kí àwa kí ó lọ, kí a sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo agbára wa ní ìgbà ìkẹhìn yĩ, nítoríkíyèsĩ, òpin súnmọ́ tòsí, ìgbà ìkẹhìn sì nìyí tí èmi yíò pa ẹ̀ka ọgbà-àjàrà mi. Fi àwọn ẹ̀ka nã bọ ãrín igi; bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó kẹ́hìn kí nwọ́n lè jẹ́ èkíní, àti kí èkíní lè jẹ́ ìkẹhìn, kí o sì wa ilẹ̀ yí àwọn igi nã ká, gbígbó àti ọ̀dọ́, èkíní àti ìkẹhìn; àti ìkẹhìn àti èkíní, kí gbogbo nwọn lè di títọ́jú lẹ́ẹkan síi fún ìgbà ìkẹhìn. Nítorí-èyi, wa ilẹ̀ yí wọn ká, kí o sì pa ẹ̀ka nwọn, kí o sì fi ajílẹ̀ sí wọn lẹ̃kan síi, fún ìgbà ìkẹhìn, nítorítí ìgbà òpin ti dé tán. Tí ó bá sì jẹ́ bẹ̃ wípé àwọn ẹ̀ka ifibọ wọ̀nyí yíò hù, kí nwọn sì so èso àdánidá jáde, nígbànã ni àwa yíò tún ọ̀nà ṣe fún nwọn, kí nwọn kí o lè dàgbà. Bí nwọn bá sì ti ndàgbà, ẹ̀nyin yíò gbá àwọn ẹ̀ká tí ó nso èso kíkorò kúrò gẹ́gẹ́bí agbára èyí tí ó dára, àti títóbi rẹ̀; ẹ̀nyin kò sì ní gbá àwọn tí kò dára níbẹ̀ kúrò lẹ̃kanṣoṣo, kí gbòngbò rẹ̀ má bã lágbára ju ẹ̀ka ifibọ, àti kí ẹ̀ka ifibọ má bã parun, kí èmi má bã sì pàdánù awọn igi ọgbà-àjàrà mi. Ó sì bà mí nínú jẹ́ wípé èmi yíò pàdánù awọn igi ọgbà-àjàrà mi; nítorí-èyi ìwọ yíò gbá èyítí ó jẹ́ búburú kúrò gẹ́gẹ́bí èyítí ó jẹ́ rere yíò ṣe hù, kí gbòngbò àti orí lè wa ní ọgbọ̣́gba nínú agbára, títí rere yíò borí búburú, tí a ó sì ké búburú lulẹ̀ kí a sì sọọ́ sínú iná, kí nwọn kí ó máṣe fún ilẹ̀ ọgbà-àjàrà mi pa; báyĩ ni èmi yíò sì ṣe gbá búburú kúrò nínú ọgbà-àjàrà mi. Ẹ̀ka igi àdánidá ni èmi yíò tún ṣe fífibọ sí inú igi àdánidá; Àwọn ẹ̀ka igi àdánidá ni èmi yíò sì fibọ̀ sínú àwọn ẹ̀ka àdánidá igi nã; báyĩ ni èmi yíò sì kó nwọn jọ lẹ̃kan síi, tí nwọn yíò sì so èso àdánidá jáde, nwọn yíò sì jẹ́ ọkan. Èyítí kò dára ni a ó sì jù dànù, bẹ̃ni, àní kúrò nínú gbogbo ilẹ̀ ọgbà-àjàrà mi; nítorí kíyèsĩ, ẹ̃kan yĩ ni èmi yíò pa ẹ̀ka igi ọgbà-àjàrà mi. Ó sì ṣe, tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì ran ìránṣẹ́ rẹ̀; ìránṣẹ́ nã sì lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́bí Olúwa nã ti pàṣẹ fún un, ó sì mú àwọn ìránṣẹ́ míràn wa; nwọn kò sì pọ̀. Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì sọ fún nwọn pé: Ẹ lọ, kí ẹ sì ṣiṣẹ́ nínú ọgbà-àjàrà nã, pẹ̀lú agbára yin. Nítorí kíyèsĩ, èyí ni ìgbà ìkẹhìn tí èmi yíò ṣe ìtọ́jú ọgbààjàrà mi; nítorítí òpin ti dé tán, àkókò nã sì nsúré tete bọ̀ wá; tí ẹ̀yin bá sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbára yín pẹ̀lú mi, ẹ̀yin yíò ní ayọ̀ nínú èso nã tí èmi yíò ko pamọ́ fún ara mi di ìgbà nã tí kò ní pẹ́ dé. Ó sì ṣe tí àwọn ìránṣẹ́ nã sì lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbára wọn; Olúwa ọgbà-àjàrà nã sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn; nwọ́n sì ṣe ìgbọràn sí àwọn òfin Olúwa ọgbà-àjàrà nã nínú ohun gbogbo. Èso àdánidá sì bẹ̀rẹ̀sí yọ jáde nínú ọgbà-àjàrà nã; ẹ̀ka àdánidá nã sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà nwọn sì yè dáradára; àwọn asọdigbó sì bẹ̀rẹ̀sí di kíké kúrò áti jíjù nù; nwọ́n sì jẹ́ kí gbòngbò àti orí igi wà ní ọgbọ̣́gba, gẹ́gẹ́bí agbára rẹ̀. Báyĩ ni nwọ́n ṣe lãlã pẹ̀lú àìsimi gbogbo, gẹ́gẹ́bí àṣẹ Olúwa ọgbà-àjàrà nã, àní títí a fi ju èyí búburú nù kúrò nínú ọgbààjàrà nã, tí Olúwa ti fi pamọ́fún ara rẹ̀ pé kí àwọn igi nã tún padà di èso àdánidá; tí nwọ́n sì padà di ẹ̀yà ara kanṣoṣo; tí àwọn èso sì jẹ́ ọgbọ̣́gba; tí Olúwa ọgbà-àjàrà nã ti fi èso àdánidá, èyítí ó níye lórí jùlọ, fún ara rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀. Ó sì ṣe, nígbàtí Olúwa ọgbà-àjàrà nã ríi pé èso nã dára, àti pé ọgbà-àjàrà rẹ̀ kò díbàjẹ́ mọ́, ó pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ, fún ìgbà ìkẹhìn yí ni àwa ti tọ́jú ọgbà-àjàrà mi; ẹ̀yin sì ríi wípé èmi ti ṣe gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú mi; èmi sì ti tọ́jú èso àdánidá rẹ̀ tí ó dára, àní gẹ́gẹ́bí ó ṣe rí ní ìbẹ̀rẹ̀. Alábùkún-fún sì ni ẹ̀yin; nítorítí ẹ̀yin ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú mi láìsinmi nínú ọgbà-àjàrà mi, ẹ̀yin sì ti pa àwọn òfin mi mọ́, ẹ̀yin sì tún ti mú èso àdánidá padà fún mi, tí ọgbà-àjàrà mi kò díbàjẹ́ mọ́, a sì ti da èyí tí ó burú nù, kíyèsĩ, ẹ̀nyin yíò ní ayọ̀ pẹ̀lú mi nítorí èso inú ọgbà-àjàrà mi. Nítorí kíyèsĩ, fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni èmi yíò ṣe àkójọ èso ọgbààjàrà mi fún ara mi di àkókò nã, èyítí ó dé kánkán; àti pé fún ìgbà ìkẹhìn ni èmi ti ṣe ìtọ́jú ọgbà-àjàrà mi, tí mo pa ẹ̀ka rẹ̀, tí mo wa ilẹ̀ yĩ ká, tí mo sì yĩ ní ọ̀rá; nítorí-èyi, ni èmi yíò kó èso rẹ̀ jọ fún ara mi fún ìgbà pípẹ́, gẹ́gẹ́bí èyí tí èmi ti sọ. Nígbàtí àkokò nã bá sì dé tí èso ibi yíò tún padà wá sí inú ọgbà-àjàrà mi, ìgbà nã ni èmi yíò jẹ́ kí a kó èso rere àti búburú jọ; èyítí ó jẹ́ rere ni èmi yíò ṣe ìtọ́jú fún ara mi, èyítí ó jẹ́ búburú ni èmi yíò sọ dànù sí ãyè ara rẹ̀. Nígbànã ni àkókò àti òpin yíò sì dé; ọgbà-àjàrà mi ni èmi yíò sì ní kí á jó pẹ̀lú iná. 6 Olúwa yíò gba Ísráẹ́lì padà ní ọjọ́ ìkẹhìn—A ó fi iná jó ayé—Ènìyàn gbọdọ̀ tẹ̀lé Krístì kí o bã yẹra fún adágún iná àti imí ọjọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, ẹ̀yin arakunrin mi, gẹ́gẹ́bí mo ti sọ fún yin pé èmi yíò sọtẹ́lẹ̀, ẹ kíyèsĩ, èyí yĩ ni ìsọtẹ́lẹ̀ mi—wípé àwọn nkan tí wòlĩ Sénọ́sì dájúdájú yĩ sọ, nípa ará ilé Ísráẹ́lì, nínú èyítí ó fi nwọ́n we igi ólífì tí a ti tọ́jú, gbọdọ̀ ṣẹ. Àti ọjọ́ nã tí òun yíò tún na ọwọ́ rẹ̀ nígbà kejì láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, ní ọjọ́ nã, bẹ̃ni, àní ìgbà ìkẹhìn, tí àwọn ìránṣẹ́ Olúwa yíò jáde lọ nínú agbára rẹ̀, láti ṣe ìtọ́jú àti pẹka ọgbà-àjàrà rẹ̀; àti lẹ́hìn èyí yĩ ni ìgbà òpin yíò dé tán. Báwo ni nwọ́n ṣe jẹ́ alábùkún- fún to, àwọn ti nwọ́n ti ṣiṣẹ́ tọkàn-tara nínú ọgbà-àjàrà rẹ̀; báwo sì ni nwọ́n ṣe jẹ́ ẹni-ìdálẹ́bi to, àwọn tí a ó ta dànù sí àyè ara wọn! Tí a ó sì jó ayé pẹ̀lú iná. Báwo sì ni Ọlọ́run wa ṣe ní ãnú fún wa tó, nítorítí ó rántí ará ílé Ísráẹ́lì, àti àwọn gbòngbò àti àwọn ẹ̀ka; ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí wọn ní gbogbo ọjọ́; nwọ́n sì jẹ́ ènìyàn ọlọ́rùn-líle àti asọ̀rọ̀-òdì; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ti nwọn kò bá sé ọkàn nwọn le ni a o gbàlà nínú ìjọba Ọlọ́run. Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo bẹ̀ yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn wípé kí ẹ̀yin kí ó ronúpìwàdà, kí ẹ sì wá tọkàntọkàn, kí ẹ sì rọ̀ mọ́ Ọlọ́run, bí òun ṣe rọ̀ mọ́ ọ yín. Nígbàtí ó bá sì na apá ãnú rẹ̀ sí i yín nínú ìmọ́lẹ̀ ọjọ́, ẹ máṣe sé ọkàn yín le. Bẹ̃ni, ní òní, tí ẹ̀yin yíò bá gbọ́ ìpè rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn yín le; kíni ìdí tí ẹ̀yin yíò ṣe fẹ́ láti kú? Ẹ kíyèsĩ, lẹ́hìn tí a ti fún un yín ní ìtọ́jú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ọjọ́ gbogbo, njẹ́ ẹ̀yin yíò mú èso búburú jáde wá, kí a bã lè ké yín lulẹ̀, kí a sì sọ yín sínú iná? Ẹ kíyèsĩ, njẹ́ ẹ̀yin yíò kọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀ bí? Njẹ́ ẹ̀yin yíò kọ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ sílẹ̀ bí; njẹ́ ẹ̀yin yíò sì tún kọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí a ti sọ nípa Krístì, lẹ́hìn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀; tí nwọn sì sẹ́ ọ̀rọ̀ rere Krístì, àti agbára Ọlọ́run, àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, kí ẹ sì pana Ẹ̀mí Mímọ́, kí ẹ sì fi ìlànà ìràpadà nlá nã ṣẹ̀sín, èyítí a ti ṣe ìlànà rẹ̀ fún yín? Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé bí ẹ̀yin bá ṣe àwọn ohun wọ̀nyí, pé agbára ìràpadà àti àjĩnde, tí ó wà nínú Krístì, yíò mú yín dúró pẹ̀lú ìtìjú àti ìdálẹ́bi tí ó burú níwájú itẹ Ọlọ́run. Àti pé, gẹ́gẹ́bí agbára àìṣègbè, nítorítí a kò lè sẹ́ àìṣègbè, ẹ̀yin níláti lọ sínú adágún iná àti imí ọjọ́ nã, èyítí a kò lè pa ọwọ́ iná rẹ̀, àti èyítí ẽfín rẹ gòkè lọ títí láéláé, adágún iná àti imí ọjọ́ èyítí íṣe oró àìnípẹ̀kun. A! njẹ, ẹ̀yin ará mi àyànfẹ́, ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì wọ ẹnu ọ̀nà híhá nã, kí ẹ sì tẹ̀síwájú nínú ọ̀nà èyítí íṣe tọ́ró, títí ẹ̀yin yíò rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà. A! sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n; kíni èmi tún lè sọ síi? Ní àkótán, mo kí yin pé ó dìgbàkan ná, títí èmi yíò pàdé yín níwájú itẹ Ọlọ́run èyítí ó láyọ̀, èyítí yíò kọlũ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìbẹ̀rù-bojo àti ìjayà. Àmín. 7 Ṣẹ́rẹ́mù sẹ́ Krístì, ó bá Jákọ́bù jà, ó bẽrè fún àmì, Ọlọ́run sì kọlũ—Gbogbo àwọn wòlĩ ti sọ̀rọ̀ nípa Krístì àti ètùtù rẹ̀—Àwọn ará Nífáì gbé ìgbé ayé nwọn gẹ́gẹ́bí alárìnkiri, a bí wọn nínú lãlã, àwọn ará Lámánì sì korira wọn. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn tí ọdún díẹ̀ ti kọjá lọ, ọkùnrin kan sì jáde wá ní ãrín àwọn ará Nífáì tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Ṣẹ́rẹ́mù. Ó sì ṣe tí, ó bẹ̀rẹ̀sí wãsù ní ãrín àwọn ènìyàn nã, àti láti kéde fún nwọn wípé kò yẹ kí Krístì wà. Ó sì wãsù ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ẹ̀tàn sí àwọn ènìyàn nã; èyí ni ó sì ṣe kí ó lè bi ẹ̀kọ́ Krístì ṣubú. Ó sì ṣe lãlã taratara kí ó lè darí ọkàn àwọn ènìyàn nã kúrò, tóbẹ̃ tí ó darí ọkàn púpọ̀ kúrò; tí òun sì mọ̀ wípé èmi, Jákọ́bù, ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì ẹnítí ó nbọ̀, ó wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà láti tọ̀ mí wá. Ó sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n, tí ó fi ní ìmọ̀ pípé nínú èdè àwọn ènìyàn nã; nítorí-èyi ó lè lo ẹ̀tàn púpọ̀, àti agbára ọ̀rọ̀ sísọ, gẹ́gẹ́bí ti agbára àrékérekè èṣù. Ó sì ní ìrètí láti yí ọkàn mi padà kúrò nínú ìgbàgbọ́ nã l’áìṣírò fún àwọn ìfihàn àti àwọn ohun púpọ̀ tí mo ti rí nípa àwọn nkan wọ̀nyí; nítorítí èmi ti rí àwọn ángẹ́lì nítòọ́tọ́, nwọ́n sì ti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún mi. Àti pẹ̀lú, mo ti gbọ́ ohùn Olúwa tí ó sì nbá mi sọ̀rọ̀ ní pàtó ọ̀rọ̀, láti ìgbà dé ìgbà; nítorí-èyi, ọkàn mi kò lè yí padà. Ó sì ṣe, tí ó tọ̀ mí wá, báyĩ ni ó sì bá mi sọ̀rọ̀, pé: Arákùnrin Jákọ́bù, èmi ti wá ãyè láti bá ọ sọ̀rọ̀; nítorítí èmi ti gbọ́ mo sì mọ̀ pẹ̀lú pé ìwọ nkãkiri lọ́pọ̀lọpọ̀, o nwãsù nípa èyítí ò npè ní ìhìn-rere, tàbí ẹ̀kọ́ Krístì. Ìwọ sì ti darí púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí kí wọn lè lòdì sí ọ̀nà òtítọ́ Ọlọ́run, kí wọn má sì pa òfin Mósè mọ́ èyítí ó jẹ́ ọ̀nà tí ó tọ́; kí wọn sì yí òfin Mósè padà sí sísin ẹ̀dá kan èyítí ìwọ sọ wípé ó nbọ̀wá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgọ̣́rún ọdún sí àkókò yí. Àti nísisìyí, kíyèsĩ èmi, Ṣẹ́rẹ́mù, sọ fún ọ wípé ọ̀rọ̀ àìtọ́ ni èyí; nítorítí ẹnìkan kò mọ̀ nípa ohun bẹ̃; nítorítí kò lè sọ nípa àwọn ohun tí ó nbọ̀wá. Báyĩ sì ni Ṣẹ́rẹ́mù gbógun tì mí. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Olúwa Ọlọ́run tú Ẹ̀mí rẹ̀ jáde sínú ọkàn mi, tóbẹ̃gẹ́ tí mo fi dãmú rẹ̀ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì wí fún un: Ìwọ ha nsẹ́ Krístì èyítí ó nbọ̀? Ó sì wípé: Tí Krístì kan yíò bá wà èmi kò ní sẹ́ẹ; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ wípé kò sí Krístì kankan, bẹ̃ni kò sí rí, kò sì lè sí láéláé. Èmi sì wí fún un: Njẹ́ ìwọ gba àwọn ìwé-mímọ́ gbọ́? Òun sì wípé, bẹ̃ni. Èmi sì wí fún un: Nígbànã nwọn kò yé ọ; nítorítí nwọ́n jẹ́rĩ sí Jésù Krístì nítòọ́tọ́. Kíyèsĩ, mo wí fún ọ pé kò sí nínú àwọn wòlĩ tí ó ti kọ tàbí tí ó sọ tẹ́lẹ̀ bíkòṣepé nwọ́n ti sọ nípa Krístì yĩ. Èyí nìkan sì kọ́—a ti fíi hàn mí, nítorítí mo ti gbọ́ mo sì ti ri; a sì ti fíi hàn mí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́; nítorí-èyi, èmi mọ̀ pé tí kò bá sí ètùtù, gbogbo aráyé ni yíò ṣègbé. Ó sì ṣe tí, ó wí fún mi pé: Fi àmì kan hàn mí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ yìi nípasẹ̀ ẹnití ìwọ ní ìmọ̀ púpọ̀. Èmi sì sọ fún un: Kíni èmi tí èmi yíò dán Ọlọ́run wò pé kí ó fi àmi kan hàn ọ́ nínú ohun tí ìwọ mọ̀ pé òtítọ́ ni? Síbẹ̀, ìwọ yíò sẹ́ ẹ, nítorípé ìwọ jẹ́ ti èṣù. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, kĩ ṣe ìfẹ́ mi ni kí a ṣe; ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run yíò bá kọlũ ọ́, kí èyí jẹ́ àmì fún ọ wípé ó ní agbára, ní ọ̀run àti ní ayé; àti pé, Krístì yíò wá. Àti pé, ìfẹ́ tìrẹ, A! Olúwa, ni kí a ṣe, kĩ sĩ ṣe tèmi. Ó sì ṣe, pé nígbàtí èmi, Jákọ́bù, ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, agbára Olúwa wá sórí rẹ̀, tó bẹ̃gẹ́ tí ó ṣubú lulẹ̀. Ó sì ṣe tí a bọ́ ọ fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀. Ó sì ṣe tí ó sì sọ fún àwọn ènìyàn nã, wípé: Ẹ péjọ ní ọ̀la, nítorítí èmi yíò kú; nítorí-èyi, mo ní ìfẹ́ láti bá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀ kí èmi ó tó kú. Ó sì ṣe pé ní ọjọ́ kejì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ pọ̀; ó sì bá nwọn sọ̀rọ̀ ní kedere, ó sì kọ̀ àwọn nkan wọnnì tí ó ti kọ́ nwọn, ó sì jẹ́rĩ Krístì nã, àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́, àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì. Ó sì bá nwọn sọ̀rọ̀ ní kedere, wípé a ti ṣi òun lọ́nà nípasẹ̀ agbára èṣù. Ó sì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run àpãdì, àti ayérayé àti ìyà ayérayé. Ó sì wípé: Mo bẹ̀rù pé kí èmi ó ma ti dá ẹ̀ṣẹ̀ àìnídàríjì nnì, nítorítí mo ti purọ́ mọ́ Ọlọ́run; nítorítí mo sẹ́ Krístì, mo sì sọ wípé mo ti gba àwọn ìwé-mímọ́ nã gbọ́; bẹ̃ nwọn jẹ́rĩ rẹ̀ nítoótọ́. Àti nítorípé èmi ti purọ́ báyĩ sí Ọlọ́run, mo bẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ọ̀rọ̀ mi ma bã burú jọjọ; ṣùgbọ́n èmi jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run. Ó sì ṣe, nígbàtí ó ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yí, kò lè sọ̀rọ̀ mọ́ ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀. Nígbàtí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nã ti ríi wípé ó sọ àwọn nkan wọ̀nyí ní kété tí ó fẹ́rẹ̀ kú, ẹnu yà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀; tó bẹ̃gẹ̃ tí agbára Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ sórí nwọn, ó sì borí nwọn tóbẹ̃ tí nwọ́n ṣubú lulẹ̀. Nísisìyí, ìṣẹ̀lẹ̀ yĩ dùnmọ́ èmi, Jákọ́bù, nítorítí mo ti bẽrè bẹ̃ lọ́wọ́ Bàbá mi tí nbẹ ní ọ́run; nítorítí ó gbọ́ igbe mi, ó sì dáhùn àdúrà mi. Ó sì ṣe tí àlãfíà àti ìfẹ́ Ọlọ́run padà sãrin àwọn ènìyàn nã; nwọ́n sì wádĩ àwọn ìwé mímọ́, nwọ́n kò sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ọkùnrin búburú yĩ mọ́. Ó sì ṣe, tí a lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà láti mú àwọn ará Lámánì padà sí ípò ìmọ̀ òtítọ́; ṣùgbọ́n asán ni ó já sí, nítorítí nwọn ní inúdídun nínú ogun àti ìtàjẹ̀sílẹ̀, nwọ́n sì ní ìkórìrà àilópin sí wa, àwọn arákùnrin nwọn. Nwọ́n sì nwá ọ̀nà nípa agbára ohun ìjà nwọn, láti pa wá run láìdẹ́kun. Nítorí-èyi, àwọn ará Nífáì gbáradì dè nwọ́n pẹ̀lú àwọn ohun ìjà nwọn, àti pẹ̀lú gbogbo agbára nwọn, ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run àti àpáta ìgbàlà nwọn; nítorí-èyi, nwọ́n di aṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá nwọn. Ó sì ṣe, tí èmi, Jákọ́kù, bẹ̀rẹ̀sí darúgbó; tí a sì nṣe àkọsílẹ̀ ìwé ìrántí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lórí àwo Nífáì míràn, nítorí-èyi, mo parí ìwé ìrántí yĩ, mo sì nsọ wípé mo ti kọọ́ gẹ́gẹ́bí ìmọ mi tí ó dárajùlọ, nípa sísọ pé àsìkò ti kọjá lọ pẹ̀lú wa, àti pé ìgbà ayé wa kọjá lọ bí ẹni wípé àwa nlá àlá, nítorípé a sì jẹ́ aláìlárá àti ọlọ́wọ̀ ènìyàn, alárìnkiri, ẹnití a lé jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù, tí a bí nínú ìpọ́njú, nínú aginjù, tí àwọn arákùnrin wa sì koríra wa, èyítí ó fa àwọn ogun àti àwọn ìjà; nítorí-èyi àwa ṣọ̀fọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Ati èmi, Jákọ́bù, sì ríi pé nkò ní pẹ́ lọ sí isà òkú; nítorí-èyi, mo wí fún ọmọkùnrin mi, Énọ́sì, pé: Gba àwọn àwo wọ̀nyí. Èmi sì sọ àwọn ohun tí Nífáì arákùnrin mi ti pa láṣẹ fún mi, ó sì ṣèlérí ìgbọràn sí àwọn àṣẹ nã. Mo sì dẹ́kun ìwé kíkọ sórí àwọn àwo wọ̀nyí, ìwé kíkọ èyítí ó kéré; si akàwé, mo kí ọ pé ó dìgbóṣe, ní ìrètí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn arákùnrin mi yíò ka àwọn ọ̀rọ̀ mi. Ẹ̀yin arákùnrin, ó dìgbóṣe. 1 Énọ́sì gbàdúrà gidigidi ó sì gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—Ohùn Olúwa wá sí ọkàn rẹ̀, tí ó nṣèlérí ìgbàlà fún àwọn ará Lámánì ní ọjọ́ iwájú—Àwọn ara Nífáì wá ọ̀nà láti mú àwọn ará Lámánì padà—Énọ́sì yọ̀ nínú Olùràpadà rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 420 kí a tó bí Olúwa wa. KÍYÈSĨ, ó sì ṣe, tí èmi, Énọ́sì, nínú ìmọ̀ wípé bàbá mi jẹ́ ẹni tí ó tọ́—nítorítí ó kọ́ mi nínú èdè rẹ̀, pẹ̀lú nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Olúwa—ìbùkún sì ni fún orúkọ Ọlọ́run mi fún èyí— Èmi ó sì sọ fún nyín ti ìjàkadì tí èmi jà níwájú Ọlọ́run, kí èmi tó gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi. Kíyèsĩ, mo lọ dọdẹ ẹranko nínú igbó; àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sábà máa ngbọ́ tí bàbá mi nsọ nípa ìyè àìnípẹ̀kun, àti ayọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, sì wọ ọkàn mi lọ. Ẹ̀mí mi si kébi; mo sì kúnlẹ̀ níwájú Ẹlẹ́da mi, mo sì kígbe pẽ nínú ọ̀pọ̀ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ tí ó lágbára fún ẹ̀mí ara mi; àti ní gbogbo ọjọ́ ni èmi kígbe pè é; bẹ̃ni, nígbàtí alẹ́ sì lẹ́, èmi sì tún gbé ohùn mi sókè tí ó fi dé àwọn ọ̀run. Ohùn kan sì tọ̀ mí wá, tí ó wípé: Énọ́sì, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, a ó sì bùkún ọ. Èmi, Énọ́sì sì mọ̀ wípé Ọlọ́run kò lè purọ́; nítorí-èyi, a ti gbá ẹ̀bi mi lọ. Mo sì wípé: Olúwa, báwo ni a ṣe ṣe èyĩ? Ó sì wí fún mi pé: Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Krístì, ẹnití ìwọ kò gbọ́ tàbí rí rí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sì kọjá lọ kí ó tó di pé yíò fi ara rẹ̀ hàn ní ẹran ara; nítorí ìdí èyí, máa lọ, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Nísisìyí, ó sì ṣe, nígbàtí èmi ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, mo bẹ̀rẹ̀sí ní ìfẹ́ fún àlãfíà àwọn arákùnrin mi, àwọn ará Nífáì; nítorí-èyi, èmí gbé gbogbo ẹ̀mí mi ka iwájú Ọlọ́run nítorí nwọn. Nígbàtí mo sì ngbìyànjú nínú ẹ̀mi báyĩ, kíyèsĩ, ohùn Olúwa tún tọ̀ mí wá, wípé: Èmi yíò bẹ àwọn arákùnrin rẹ wò, gẹ́gẹ́bí àìsimi wọn nípa pípa àwọn òfin mi mọ́. Mo ti fún nwọn ní ilẹ̀ yí, ó sì jẹ́ ilẹ̀ mímọ́; èmi kò sì ní fi ré, bíkòṣepé nípasẹ̀ ìwà àìṣedẽdé; nítorí-èyi, èmi yíò bẹ àwọn arákùnrin rẹ wò gẹ́gẹ́bí èyí tí mo ti sọ; ìwà ìrékọjá nwọn ni èmi yíò si mú wá pẹ̀lú ìbànújẹ́ sí orí ara nwọn. Àti lẹ́hìn tí èmi, Énọ́sì, ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ìgbàgbọ́ mi bẹ̀rẹ̀ sì fi ẹsẹ̀múlẹ̀ nínú Olúwa; èmi sì gbàdúrà síi pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìgbìyànjú pípẹ́ fún àwọn arákùnrin mi, àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí èmi ti gbàdúrà tí mo sì ti ṣiṣẹ́ láìsinmi, Olúwa sì wí fún mi pé: Èmi yíò fifún ọ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ, nítorí ìgbàgbọ́ rẹ. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, èyí ni ìfẹ́-inú mi tí mo fẹ́ kí ó ṣe—pé bí ó bá lè ri bẹ̃, ti àwọn ènìyàn mi, àwọn ará Nífáì, bá ṣubú sí inú ìwà ìrékọjá, tí a sì pa wọ́n run lọ́nàkọnà, àti, tí a kò sì pa àwọn ará Lámání run, pé kí Olúwa Ọlọ́run ṣe ìtọ́jú ìwé ìrántí àwọn ènìyàn mi, àwọn ará Nífáì; pãpã bí ó tilẹ̀ jẹ́ nípa agbára ọwọ́ rẹ̀ mímọ́, kí a lè múu jáde níìgbà kan ní ọjọ́ iwájú sí àwọn ará Lámánì, pé, bóyá, a o lè mú nwọn wá sínú ìgbàlà— Nítorípé lọ́wọ́lọ́wọ́ gbogbo ìgbìyànjú wá jẹ́ asán ní mímú nwọn padà sí inú ìgbàgbọ́ òdodo. Nwọ́n sì búra nínú ìbínú nwọn pé, bí ó bá ṣeéṣe, nwọn yíò pa ìwé ìrántí wa àti àwa run, àti gbogbo àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn bàbá wa. Nítorí-èyi, nítorítí mo mọ̀ wípé ó rọrùn fún Olúwa Ọlọ́run láti pa àwọn ìwé ìrántí wa mọ́, mo kígbe pẽ l’áìsimi, nítorítí òun ti sọ fún mi wípé: Ohunkóhun tí ìwọ yíò bá bẽrè pẹ̀lú ìgbàgbọ́, tí o sì gbàgbọ́ pé ìwọ yíò rí gbà ní orúkọ Krístì, ìwọ yíò rí gbà. Èmi sì ní ìgbàgbọ́, mo sì kígbe pe Ọlọ́run pé kí ó pa àwọn ìwé ìrántí nã mọ́; Òun sì bá mi dá májẹ̀mú pé Òun yíò mú wọn jáde sí àwọn ará Lámánì ní àkokò tí ó yẹ níti rẹ̀. Èmi, Énọ́sì, sì mọ̀ wípé yíò rí gẹ́gẹ́bí májẹ̀mú tí ó ti dá; nítorínã, ẹ̀mí mi simi. Olúwa sì wí fún mi pé: Àwọn bábá rẹ nã ti bẽrè ohun yĩ lọ́wọ́ mi; yíò sì rí fún nwọn gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ nwọn; nítorítí ìgbàgbọ́ nwọn dàbí ti yín. Àti nísisìyí, ó sì ṣe, tí èmi Énọ́sì nlọ kiri lãrín àwọn ará Nífáì, tí mò nsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tí nbọ̀wá, tí mo sì njẹ́rĩ sí àwọn ohun tí mo ti gbọ́ àti èyítí mo ti rí. Mo sì jẹ́rĩ pé àwọn ará Nífáì fi tọkàn-tọkàn wá ọ̀nà láti mú àwọn ará Lámánì padà sínú ìgbàgbọ́ òtítọ́ nínú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n lãlã wa já sí asán; ikorira wọn kò yẹ̀, ìwà búburú nwọn sì ndarí nwọn tí wọ́n fi di ẹhànnà, ònrorò àti ẹnití òngbẹ ẹ̀jẹ̀ ngbẹ, nwọn kún fún ìwà ìbọ̀rìṣà àti ẽrí; ti nwọn sì njẹ ẹranko tí npẹran jẹ; tí nwọn ngbé inú àwọn àgọ́, tí nwọ́n sì nrìn kiri nínú aginjù nínú ìbàntẹ́, tí nwọn sì fá orí nwọn; nwọ́n sì já fáfá nínú lílo ọrún, àti simetà àti ãké. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nwọn kò sì jẹ ohun míràn àfi ẹran tútù; nwọ́n sì nlépa àti pa wa run láìdẹ́kun. Ó sì ṣe, tí àwọn ará Nífáì sì dáko, nwọ́n sì gbin oríṣiríṣi irúgbìn, pẹ̀lú èso, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀wọ́ agbo ẹran, àti ọ̀wọ́ onírurú màlũ, àti ewúrẹ́, àti ewúrẹ́ igbó, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin. Àwọn wòlĩ tí ó pọ̀ púpọ̀ si wà lãrín wa. Àwọn ènìyàn nã sì jẹ́ ọlọ́rùn-líle ènìyàn, tí òyè kò sì yé nwọn. Kò sì sí ohun míràn bí kò ṣe ọ̀pọ̀ ìrorò, ìwãsù àti ìsọtẹ́lẹ̀ ogun àti ìjà, àti ìparun, àti rírán nwọn létí ikú láìdẹ́kun, àti àkokò ayé àìnípẹ̀kun, àti ìdájọ́ àti agbára Ọlọ́run, àti gbogbo nkan wọ̀nyí—nta wọ́n jí láìdẹ́kun, kí nwọ́n lè wà nínú ìbẹ̀rù Olúwa. Mo ní kò sí èyítí ó yàtọ̀ sí ohun wọ̀nyí, àti ọ̀rọ̀ tí ó ṣe kedere, tí ó lè mú kí nwọn má ṣègbé ní kánkán. Báyĩ ni èmi sì ṣe kọ ìwé nípa wọn. Mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì nínú ìgbésí ayé mi. Ó sì ṣe nígbàtí mo bẹ̀rẹ̀ sĩ darúgbó, tí ọgọ̣́rún àti ãdọ́rin àti mẹ́sán ọdún ti kọjá lọ láti ìgbà t í bàbá wa Léhì t i f i Jerúsálẹ́mù sílẹ̀. Mo sì ríi pé ọjọ́ súnmọ́ tí èmi yíò lọ sínú sàrẽ mi, lẹ́hìn tíagbára Ọlọ́run sì ti ràdọ̀bò mí pé mo níláti wãsù, àti sọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn yĩ, kí èmi sì kéde ọ̀rọ̀ nã gẹ́gẹ́bí òtítọ́ èyítí ó wà nínú Krístì. Èmi sì ti kéde rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mi, mo sì ti yọ̀ nínú rẹ̀ ju ti ayé yĩ. Èmi yíò sì lọ sí ibi ìsimi mi láìpẹ́, èyítí ó wà pẹ̀lú Olùràpadà mi; nítorítí èmi mọ̀ pé nínú rẹ̀ ni èmi yíò simi. Èmi sì yọ̀ nínú ọjọ́ nã tí ara mi yíò gbé àìkú wọ̀, tí yíò sì dúró ní iwájú rẹ̀; nígbànã ni èmi yíò rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú inúdídùn, òun yíò sì wí fún mi pé: Wá sí ọ̀dọ̀ mi, ìwọ alábùkún-fún, a ti pèsè ãyè sílẹ̀ fún ọ nínú ilé Bàbá mi. Àmin. 1 Àwọn ará Nífáì pa òfin Mósè mọ́, nwọn nretí bíbọ̀ Krístì, nwọ́n sì ṣe rere ní ilẹ̀ nã—Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlĩ ni nwọ́n siṣẹ́ láti mú àwọn ènìyàn nã dúró ní ọ̀nà òdodo. Ní ìwọ̀n ọdún 399 sí 361 kí a tó bí Olúwa wa. NÍSISÌYÍ ẹ kíyèsĩ, èmi, Járọ́mù, kọ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ gẹ́gẹ́bí àṣẹ bàbá mi, Énọ́sì, kí a bã pa ìtàn ìdílé wa mọ́. Nítorípé àwọn àwo wọ̀nyí kéré, àti nítorípé a kọ àwọn nkan wọ̀nyí fún ànfãní àwọn arákùnrin wa àwọn ará Lámánì, nítorí-èyi, ó di dandan kí èmi kọ díẹ̀; ṣùgbọ́n èmi kò ní kọ àwọn nkan ìsọtẹ́lẹ̀, tàbí àwọn ìfihàn mi. Nítorí kíni èmi ìbá tún lè kọ ju èyí tí àwọn bàbá mi tĩ kọ? Njẹ́ nwọn kò ha ti fi ìlàna ìgbàlà hàn bí? Mo wí fún nyín, Bẹ̃ni; èyí sì ti tó fún mi. Ẹ kíyèsĩ, ó yẹ kí a ṣe iṣẹ́ púpọ̀ lãrín àwọn ènìyàn yĩ, nítorítí líle ọkàn nwọn, àti dídi etí nwọn, àti rírá iyè nwọn, àti líle ọrùn nwọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Ọlọ́run ní ãnú púpọ̀ lórí nwọn, kò sì tĩ gbá nwọ́n kúrò lórí ilẹ̀. Púpọ̀ sì wà lãrín wa tí nwọ́n ní ìfihàn púpọ̀, nítorítí kĩ ṣe gbogbo nwọn nĩ ṣe ọlọ́run líle. Gbogbo àwọn tí nwọn kò sì jẹ́ ọlọ́rùn líle tí nwọ́n sì ní ígbàgbọ́, ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, ẹnití ó fi ara rẹ̀ han àwọn ọmọ ènìyàn, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ nwọn. Àti nísisìyí, sì kíyèsĩ, ọgọ̣́rún méjì ọdún ti kọjá lọ, àwọn ará Nífáì sì ti di alágbára lórí ilẹ̀ nã. Nwọ́n pa òfin Mósè mọ́ nwọn sì ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́ fún Olúwa. Nwọn kò sì sọ̀rọ̀ àìmọ́; tàbí ọ̀rọ̀ àìtọ́. Àwọn òfin ìlú nã sì tọnà púpọ̀. Nwọ́n sì gbilẹ̀ sí ibi púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àti àwọn ara Lámánì pẹ̀lú. Nwọ́n sì pọ̀ púpọ̀ ju àwọn ará Nífáì; nwọ́n sì fẹ́ràn ìpànìyàn, nwọn á sì máa mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹranko. Ó sì ṣe tí nwọ́n kọlũ àwa ará Nífáì ní ìgbà púpọ̀, láti jagun. Ṣùgbọ́n àwọn ọba wa àti àwọn olórí wa jẹ́ alágbára ènìyàn nínú ìgbàgbọ́ Olúwa; nwọ́n sì kọ́ àwọn ènìyàn nã ní ọ̀nà Olúwa; nítorí-èyi a kọjú ìjà sí àwọn ará Lámánì, a sì lé nwọn jáde kúrò lórí àwọn ilẹ̀ wa, a sì bẹ̀rẹ̀ síndábóbò àwọn ìlú wa, tàbí gbogbo ibi ohun-ìní wa. Àwa sí pọ̀ ní ìlọ́po-ìlọ́po, a sì tànká orí ilẹ̀ nã, a sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀ nínú wúrà àti fàdákà, àti nínú àwọn ohun iyebíye, àti nínú iṣẹ́ ọnà igi dáradára, ní àwọn ilé kíkọ́, àti nínú ẹ̀rọ, àti ní irin lílò, àti bàbà, àti idẹ, àti irin líle, a sì nrọ oríṣiríṣi ohun èlò tí a fi ndáko, àti ohun-ìjà ogun—bẹ̃ni, ọfà ẹlẹ́nu mímú, àti apó-ọfà, àti ọ̀kọ̀ kútúpú, àti ọ̀kọ̀, àti gbogbo ìmúrasílẹ̀ fún ogun. Nítorípé a ti múrasílẹ̀ láti dojúkọ àwọn ará Lámánì, nwọn kò borí wa. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa di jíjẹ́rĩ sí, èyítí ó sọ fún àwọn bàbá wa, wípé: Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́, ẹ̀yin yíò ṣe rere lórí ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí àwọn wòlĩ Olúwa kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn Nífáì, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pé tí nwọn kò bá pa àwọn òfin nã mọ́, tí nwọ́n sì ṣubú sínú ìwà ìrekọjá, a o pa nwọ́n run kúrò lórí ilẹ̀ nã. Nítorí-èyi àwọn wòlĩ, àti àwọn àlùfã, àti àwọn olùkọ́ nã ṣiṣẹ́ láìsinmi, ní gbígba àwọn ènìyàn níyànjú sí ìtara, pẹ̀lú ìpamọ́ra; nwọ́n nkọ́ òfin Mósè, àti ìdí tí a fifún ni; nwọn nyí nwọn lọ́kàn padà pé kí nwọ́n fojúsọ́nà sí Messia, kí nwọ́n sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ pé ó nbọ̀ bí èyítí ó ti wá. Báyĩ sì ni nwọ́n ṣe kọ́ nwọn. Ó sì ṣe tí ó jẹ́ wípé ní ṣíṣe báyĩ nwọ́n pa nwọ́n mọ́ kúrò nínú ìparun lórí ilẹ̀ nã; nítorítí nwọ́n tọ́ ọkàn nwọn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nã, nwọ́n sì ntawọ́njí láìdẹ́kun sí ìrònúpìwàdà. Ó sì ṣe tí ọgọ̣́rún méjì ọdún ó lé ọgbọ̀n àti méjọ ti kọjá—lẹ́hìn irú àwọn ogun àti ìjà, àti ìyapa fún ìwọ̀n ọjọ́ pípẹ́. Èmi, Járọ́mù, kò kọ jù bẹ̃ lọ nítorítí àwọn àwo nã kéré. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ lè lọ sí àwọn àwo ti Nífáì míràn; nítorí kíyèsĩ, lórí wọn ni a gbẹ́ àkọsílẹ̀ ìwé ìtàn àwọn ogun tí a jà sí, gẹ́gẹ́bí kíkọ ti àwọn ọba, tàbí àwọn tí nwọ́n ní kí nwọ́n kọ. Èmi sì fi àwọn àwo wọ̀nyí lé ọwọ́ ọmọ mi Ómúnì, kí a lè pa nwọ́n mọ́ gẹ́gẹ́bí àṣẹ àwọn bàbá mi. 1 Ómúnì, Ámárọ́nì, K ẹ́ m í ṣ ì , Ábínádọ́mù, àti Ámálẹ́kì, kọ ìwé ìrántí ní ọkàn lẹ́hìn ìkejì—Mòsíà ṣe alábápàdé àwọn ará Sarahẹ́múlà, tí nwọ́n wá láti Jerúsálẹ́mù ní àkókò Sẹdẹkíàh—A fi Mòsíà ṣe ọba lórí nwọn— Àwọn ọmọ Múlẹ́kì tí nwọ́n wà ní Sarahẹ́múlà ti ṣe alábápàdé Kóríántúmúrì, èyítí ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Járẹ́dì—Ọba Bẹ́njámínì rọ́pò Mòsíà—Ènìyàn níláti fi ẹ̀mí nwọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọrẹ sí Krístì. Ní ìwọ̀n ọdún 323 sí 130 kí a tó bí Olúwa wa. KÍYÈSĨ, ó sì ṣe tí èmi, Ómúnì, tí bàbá mi Járọ́mù pàṣẹ fún, pé kí èmi kọ díẹ̀ sínú àwọnàwo wọ̀nyí, fún pípa ìtàn ìdílé wa mọ́. Nítorí-èyi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, èmi fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé mo jà púpọ̀ pẹ̀lú idà fún ìpamọ́ àwọn ènìyàn mi, àwọn ará Nífáì, láti ma jẹ́ kí nwọ́n ṣubú sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, àwọn ará Lámánì. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi pãpã jẹ́ ènìyàn búburú, èmi kò sì pa àwọn ìlànà àti àwọn òfin Olúwa mọ́ bí ó ṣe yẹ ki emi ṣe. Ó sì ṣe, tí ọgọ̣́rún méjì ọdún àti ãdọ́rin àti mẹ́fà ti kọjá, a sì ní àlãfíà fún ìgbà pípẹ́; a sì ní ogun gbígbóná àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́. Bẹ̃ni, ní àkópọ̀, ọgọ̣́rún ọdún méjì àti ọgọ̣́rin àti méjì ti kọjá lọ, èmi sì ti pa àwọn àwo yĩ mọ́ gẹ́gẹ́bí àṣẹ àwọn bàbá mi; èmi sì fi nwọ́n fún ọmọ mi Ámárọ́nì. Mo sì fi òpin sĩ. Àti nísisìyí èmi, Ámárọ́nì, kọ gbogbo àwọn ohun èyíkeyĩ tí mo kọ, tí nwọ́n jẹ́ díẹ̀, sí inú ìwé bàbá mi. Kíyèsĩ, ó sì ṣe tí ọgọ̣́rún mẹ́ta àti ogun ọdún ti kọjá lọ, tí àwọn tí ó burú jù nínú àwọn ará Nífáì ti ṣègbé. Nítorítí Olúwa kì yíò jẹ́ kí nwọ́n ṣubú sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, lẹ́hìn tí ó ti mú nwọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, bẹ̃ni, kì yíò jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ ṣe aláì di mímọ̀, èyí tí ó sọ fún àwọn bàbá wa, wípé: Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kò bá pa àwọn òfin mi mọ́, ẹ̀yin kò ní ṣe rere ní orí ilẹ̀ nã. Nítorí-èyi, Olúwa bẹ̀ wọ́n wò nínú ìdájọ́ nlá; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó pa àwọn olódodo mọ́, kí nwọn ma bã parun, pẹ̀lú pé ó gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn. Ó sì ṣe, tí èmi gbé àwọn àwo nã lé arákùnrin mi Kẹ́míṣì lọ́wọ́. Nísisìyĩ èmi, Kẹ́míṣì, kọ àwọn ohun díẹ̀ tí èmi kọ, nínú ìwé kan nã pẹ̀lú arákùnrin mi; nítorí kìyésĩ, èmi rí èyí tí ó kọ gbẹ̀hìn, pé ó kọọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀; ó sì kọọ́ ní ọjọ́ tí ó fi nwọ́n lé mi lọ́wọ́. Báyĩ ni àwa ṣe kọ ìwé ìtán wọ̀nyí, nítorí ó jẹ́ gẹ́gẹ́bí àṣẹ àwọn bàbá wa. Èmi sì fi òpin si. Kíyèsĩ, Èmi, Ábínádọ́mù, jẹ́ ọmọ Kẹ́míṣì. Kíyèsĩ, ó sì ṣe tí èmi rí ogun àti ìjà lọ́pọ̀lọpọ̀ lãrín àwọn ènìyàn mi, àwọn ará Nífáì, àti àwọn ará Lámánì; èmi sì ti fi idà mi gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará Lámánì ní dídá àbò bò àwọn arákùnrin mi. Sì kíyèsĩ, ìwé ìrán àwọn ènìyàn yĩ wà ní fífín lé orí àwọn àwo tí ó wà lọ́wọ́ àwọn ọba, láti ìran dé ìran; èmi kò sì mọ́ ìfihàn míràn yàtọ̀ sí èyí tí a ti kọ, tàbí àsọtẹ́lẹ̀ míràn; nítorí-èyí: èyí tí ó tọ́ ni a ti kọ. Èmi sì fi òpin si. Kíyèsĩ, èmi ni Ámálẹ́kì, ọmọ Ábínádọ́mù. Kíyèsĩ, èmi yíò bá nyín sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa Mòsíà, ẹnití a fi jẹ ọba lórí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; nítorí kíyèsĩ, ẹnití a ti kìlọ̀ fún nípasẹ̀ Olúwa, pé kí ó sá kúrò ní ilẹ̀ Nífáì, àti pé gbogbo àwọn tí nwọn yíò gbọ́ran sí ohùn Olúwa níláti fi ìlú nã sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ, lọ sínú aginjù— Ó sì ṣe tí ó ṣe gẹ́gẹ́bí Olúwa ti pàṣẹ fún un. Nwọ́n sì fi ìlú nã sílẹ̀ lọ sínú aginjù, gbogbo àwọn tí nwọn yíò gbọ́ran sí ìpè Olúwa; a sì darí nwọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwãsù àti ìsọtẹ́lẹ̀. A sì ngbà nwọ́n ní ìyànjú nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; a sì ndarí nwọn nípa agbára ọwọ́ rẹ̀, lãrín aginjù títí nwọnfi dé inú ilẹ̀ èyítí à npè ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Nwọ́n sì ṣe alabapade àwọn ènìyàn kan láìròtẹ́lẹ̀, tí à npè ní àwọn ènìyàn Sarahẹ́múlà. Nísisìyí, àjọyọ̀ púpọ̀ wa lãrín àwọn ará Sarahẹ́múlà; Sarahẹ́múlà nã sì yọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú, nítorí Olúwa ti ran àwọn ará Mòsíà pẹ̀lú àwọn àwo idẹ èyítí a kọ ìwé ìtàn àwọn Jũ le. Kíyèsĩ, ó sì ṣe tí Mòsíà ní òye pé àwọn ará Sarahẹ́múlà wa láti Jerúsálẹ́mù ní ìgbà tí a mú Sẹdẹkíàh, ọba Júdà ní ìgbèkùn lọ sí Bábílọ́nì. Nwọ́n sì rin ìrìn àjò nínú aginjù, a sì mú wọn la omi nlá nã já nípa ọwọ́ Olúwa, sí inú ilẹ̀ nã níbití Mòsíà ṣe alabapade nwọn; nwọ́n sì ngbé ibẹ̀ láti ìgbà nã lọ. Nígbàtí Mòsíà ṣe alabapade nwọn, nwọ́n ti pọ̀ púpọ̀. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun àti ìjà púpọ̀, nwọ́n sì tì ṣubú nípasẹ̀ idà láti ìgbà dé ìgbà; èdè nwọn sì ti dàrú; nwọn kò sì mú ìwé ìtàn kankan wá pẹ̀lú nwọn; nwọ́n sì sẹ́ wíwà Ẹlẹ́dã nwọn; ati Mòsíà tàbí àwọn ènìyàn Mòsià kò lè gbọ́ wọn yé. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí Mòsíà jẹ́ kí a kọ́ nwọ́n ní èdè rẹ. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí a ti kọ́ nwọn ní èdè Mòsíà, ti Sarahẹ́múlà fún nwọn ní ìtàn ìdílé àwọn bàbá rẹ̀, gẹ́gẹ́bí ó ṣe rántí; a sì kọ wọ́n, ṣùgbọ́n kĩ ṣe sí orí àwo wọ̀nyí. Ó s ì ṣ e t í àwọn ará Sarahẹ́múlà àti ti Mòsíà, parapọ̀, a sì yan Mòsíà ni ọba nwọn. Ó sì ṣe ní àwọn ọjọ́ ti Mòsíà, a gbé òkúta nlá kan tí ó ní fífín lórí rẹ̀ tọ̣́ wá; ó sì túmọ̀ fífín nã nípa ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run. Nwọ́n sì sọ nípa Kóríántúmúrì kan, àti àwọn tí a pa nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. A sì ṣe alabapade Kọriantumuri nípasẹ̀ àwọn ará Sarahẹ́múlà; ó sì gbé pẹ̀lú nwọn ní ìwọ̀n òṣùpá mẹ́sán. Ó tún sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn bàbá rẹ̀. Àwọn òbí rẹ̀ àkọ́kọ́ sì wá láti ile ìṣọ́ gíga nã, ní ìgbà èyítí Olúwa da èdè àwọn ènìyàn nã rú; ìrorò Olúwa sì bọ́ sórí wọn gẹ́gẹ́bí ìdájọ́ rẹ̀, àwọn èyítí ó tọ́; egungun nwọn sì wà ní ìfọ́nká nínú ilẹ̀ apá àríwá. Kíyèsĩ, èmi, Ámálẹ́kì, ni a bí ní àwọn ọjọ́ ti Mòsíà; èmi sì wà títí mo fi rí ikú rẹ̀; Bẹ́njámínì, ọmọ rẹ̀, sì jọba dípò rẹ̀. Sì wọ́, èmi ti rí, ní àwọn ọjọ́ Bẹ́njámínì ọba, ogun tí ó gbóná, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì. Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì ní ànfàní púpọ̀ lórí nwọn; bẹ̃ni tóbẹ̃gẹ́ tí Bẹ́njámínì ọba lé nwọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Ó sì ṣe, tí èmi bẹ̀rẹ̀sí darúgbó; tí èmi kò sì ní irú-ọmọ, tí mo sì mọ́ wípé Bẹ́njámínì ọba jẹ́ ènìyàn tí ó tọ́ níwájú Olúwa, nítorí-èyi, èmi yíò gbé àwọn àwo nã fún un, tí mo sì ngba gbogbo ènìyàn níyànjú pé kí nwọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Ẹní Mímọ́ Ísráẹ́lì, kí nwọ́n sì gbàgbọ́ nínú ìsọtẹ́lẹ̀, àti nínú ìfihàn, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì, àti nínú ẹ̀bùn fífi èdè fọ̀, àti nínú títúmọ̀ èdè, àti nínú gbogbo ohun tí ó dára; nítórítí kò sí ohun tí ó dára bí kò bá ṣe wípé ó wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa: Èyítí ó sì jẹ́ búburú wá láti ọ̀dọ̀ èṣù. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, èmi rọ̀ yín pé kí ẹ wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, ẹnití ìṣe Ẹní Mímọ́ Ísráẹ́lì, kí ẹ́ sì pín nínú ìgbàlà rẹ̀, àti agbára ìràpadà rẹ̀. Bẹ̃ni, ẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí ẹ sì fi gbogbo ẹ̀mí yín fún un gẹ́gẹ́bí ọrẹ, kí ẹ sì tẹ̀síwájú nínú ãwẹ̀ àti àdúrà, kí ẹ sì forítì í dé òpin; gẹ́gẹ́bí Olúwa sì ti wà, a ó gbà yín là. Àti nísisìyí, èmi yíò sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tí nwọ́n lọ sínú aginjù kí nwọ́n lè padà sí ilẹ̀ Nífáì; nítorítí nwọ́n pọ̀ tí wọ́n ní ìfẹ́ láti jogún ilẹ̀ ìní nwọn. Nítorí-èyi, nwọ́n kọjá lọ sí aginjù. Olórí nwọ́n jẹ́ alágbára ènìyàn, àti ọlọ́runlíle, nítorí-èyi ó dá ìjà sílẹ̀ lãrín nwọn; a sì pa gbogbo nwọn, àfi ãdọ́ta, nínú aginjù nã, nwọ́n sì tún padà sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Ó sì ṣe tí nwọ́n túnmú àwọn díẹ̀ sĩ, nwọ́n sì tún mú ìrìnàjò nwọn lọ sínú aginjù. Èmi, Ámálẹ́kì, sì ní arákùnrin kan tí òun nã lọ pẹ̀lú nwọn; èmi kò sì mọ̀ nípa nwọn láti ìgbà nã. Èmi sì fẹ́rẹ̀ dùbúlẹ̀ nínú ibojì mi; àwọn àwo yĩ sì ti kún. Mo sì fi òpin sí ọ̀rọ̀ sísọ mi. 1 Mọ́mọ́nì ṣe ìkékúrú àwọn àwo nlá ti Nífáì—Ó fi àwọn àwo kékeré pẹ̀lú àwọn àwo yókù—Ọba Bẹ́njámínì fi àlãfíà lélẹ̀ ní ilẹ̀ nã. Ní ìwọ̀n ọdun 385 nínú ọjọ́ Olúwa wa. ÀTI nísisìyí, èmi Mọ́mọ́nì, tí mo fẹ́rẹ̀ gbé ìwé ìrántí èyítí èmi t i nkọ sí ọwọ́ ọmọ mi Mórónì, kíyèsĩ, èmi rí púpọ̀ nínú ìparun àwọn ènìyàn mi, àwọn ará Nífáì. Ó sì jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgọ̣́rún ọdún lẹ́hìn bíbọ̀ Krístì tí mo gbé àwọn ìwé ìrántí yĩ lé ọwọ́ ọmọ mi; èmi sì lérò wípé òun yíò rí gbogbo ìparun àwọn ènìyàn mi. Ṣùgbọ́n kí Ọlọ́run jẹ́ kí ó lè wà lãyè, kí ó lè kọ nípa Krístì, wípé, ní ọjọ́ kan, yíò ṣe nwọ́n ní ànfàní. Àti nísisìyí, èmi sọ̀rọ̀ nípa èyítí mo ti kọ; nítorí lẹ́hìn tí èmi ti ṣe ìkékúrú láti inú àwọn àwo ti Nífáì, títí dé ìjọba ọba Bẹ́njámínì yìi, èyítí Ámálẹ́kì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, mo ṣe àyẹ̀wò nínú àwọn ìwé ìrántí èyítí a ti gbé lé mi lọ́wọ́, èmi sì rí àwọn àwo yĩ, èyítí ó ní àkọsílẹ̀ kékeré lórí àwọn wòlĩ, láti Jákọ́bù, títí dé ìjọba ọba Bẹ́njámínì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ Nífáì. Àwọn ohun tí ó sì wà ní orí àwọn àwo yĩ dùn mọ́ mi nínú, nítorí àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ ti bíbọ̀ Krístì; àwọn bàbá mi sì mọ̀ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nwọn ni a ti múṣẹ; bẹ̃ni, èmi sì tún mọ̀ wípé gbogbo àwọn ohun tí a ti sọtẹ́lẹ̀ nípa wa títí di òni ni a ti múṣẹ, gbogbo àwọn tí ó sì kù tayọ akoko yĩ ni yíò di mimuṣẹ. Nítorí-èyi, èmi yan àwọn ohun wọ̀nyí láti parí àkọsílẹ̀ tèmi lórí nwọn, nínú àwọn èyí tí ó kù nínú ìwé ìrántí mi ni èmi yíò mú nínú àwọn àwo ti Nífáì; èmi kò sì lè kọ ìdákan nínúọgọ̣́rún àwọn ohun nípa àwọn ènìyàn mi. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi yíò mú àwọn àwo wọ̀nyí, tí wọ́n ní àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìfihàn nínú, èmi ó sì mú nwọn pọ̀ mọ́ ìyókù nínú àkọsílẹ̀ mi, nítorítí nwọ́n jẹ́ àṣàyàn fún mi; èmi sì mọ̀ wípé nwọn yíò jẹ́ àṣàyàn fún àwọn arákùnrin mi. Èmi sì ṣe èyí fún ipa ọgbọ́n; nítorítí a bámi sọ̀rọ̀ ní ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, gẹ́gẹ́bí awọn iṣẹ ti Ẹ̀mí Olúwa èyítí ó wà nínú mi. Àti nísisìyí, èmi kò sì mọ́ ohun gbogbo; ṣùgbọ́n Olúwa mọ́ ohun gbogbo tí nbọ̀wá; nítorí-èyi, ó nṣiṣẹ́ nínú mi lati ṣe gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú rẹ̀. Àdúrà mi sí Ọlọ́run ni nípa àwọn arákùnrin mi, pé nwọn lè padà wá lẹ̃kan si sí ìmọ̀ Ọlọ́run, bẹ̃ni, ìràpadà Krístì; pé nwọn lè padà jẹ́ ènìyàn rere lẹ̃kan si. Àti nísisìyí, èmi Mọ́mọ́nì, tẹ̀síwájú láti parí ìwé ìrántí mi, èyítí mo mú láti inú àwọn àwo ti Nífáì; èmi sì kọọ́ gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ àti òye ti Ọlọ́run fún mi. Nítorí-èyi, ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ámálẹ́kì ti gbé àwọn àwo wọ̀nyí lé ọwọ́ ọba Bẹ́njámínì, ó mú nwọn pẹ̀lú àwọn àwo míràn, èyítí ó ní ìwé ìrántí èyítí a ti gbé kalẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọba, láti ìran dé ìran títí dé ìgbà ọba Bẹ́njámínì. A sì gbe kalẹ̀ láti ọwọ́ ọba Bẹ́njámínì láti ìran dé ìran, títí nwọ́n fi dé ọwọ́ mi. Èmi, Mọ́mọ́nì, sì gbàdúrà sí Ọlọ́run, pé kí a lè pa nwọ́n mọ́ láti ìsisìyí lọ. Èmi sì mọ̀ wípé a ó pa nwọ́n mọ́; nítorí àwọn ohun nlá ni a kọ lé wọn lórí, nínú èyítí àwọn ènìyàn mi àti àwọn arákùnrin nwọn yíò gba ìdájọ́, ní ọjọ́ ìkẹhìn nã tí ó lágbára, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a ti kọ sílẹ̀. Àti nísisìyí, nípa ọba Bẹ́njámínì yĩ—ó ní ohun kan bí ìjà lãrín àwọn ènìyàn tirẹ̀. Ó sì ṣe bakannã, tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ará Lámánì jáde wá kúrò ní ilẹ̀ Nífáì, láti dojú ìjà kọ àwọn ènìyàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ọba Bẹ́njámínì kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó sì dojúkọ nwọ́n; ó sì bá wọn jà nínú agbára ọwọ́ rẹ̀, pẹ̀lú idà Lábánì. Pẹ̀lú agbára Olúwa ni nwọ́n sì bá àwọn ọ̀tá nwọn jà, títí nwọ́n fi pa ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí nwọ́n bá àwọn ará Lámánì jà títí nwọ́n fi lé nwọn jáde kúrò nínú gbogbo ilẹ̀ ìní nwọn. Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí àwọn Krístì ayédèrú ti kọjá lọ, tí a sì ti pa nwọ́n lẹ́nu mọ́, tí nwọ́n sì ti jìyà gẹ́gẹ́bí ìwà búburú nwọn; Lẹ́hìn tí àwọn wòlĩ èké, àti oníwãsù àti olùkọ́ni èké lãrín àwọn ènìà nã ti wà, tí a sì ti fi ìyà jẹ gbogbo àwọn wọ̀nyí, gẹ́gẹ́bí ìwà búburú nwọn; lẹ́hìn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjà àti ìyapa lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Lámánì ti wà, kíyèsĩ, ó sì ṣe tí ọba Bẹ́njámínì, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn wòlĩ mímọ́ tí nwọ́n wà lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀. Sì kíyèsĩ, ọba Bẹ́njámínì jẹ́ ẹni mímọ́, ó sì jọba lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí nínú ìwà òdodo; àwọn ẹni mímọ́ sì pọ̀ nínú ilẹ̀ nã, nwọ́n sì nsọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú agbára àti pẹ̀lú àṣẹ; nwọ́n si lo ọ̀rọ̀ líle nítorí èrèdí ọrùnlíle àwọn ènìyàn nã— Nítorí-èyi, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn wọ̀nyí, ọba Bẹ́njámínì, nípa ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ àti gbogbo ìyè ẹ̀mí rẹ̀, àti àwọn wòlĩ pẹ̀lú, sì tún dá àlãfíà padà sínú ìlú nã lẹ̃kan si. 1 Ọba Bẹ́njámínì kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ní èdè àti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ ti bàbá nwọn—Àwọn ẹ̀sìn nwọn àti ọ̀làjú nwọn ti wà ní ìpamọ́ nítorí àwọn ìwé ìrántí tí a kọ sórí onírũrú àwọn àwo—A yan Mòsíà bí ọba a sì fún un ní ìṣọ́ lórí àwọn ìwé ìrántí nã àti àwọn nkan míràn. Ní ìwọ̀n ọdún 130 sí 124 kí a tó bí Olúwa wa. ÀTI nísisìyí kò sí ìjà mọ́ nínú gbogbo ilẹ̀ Sarahẹ́múla, ní ãrin gbogbo àwọn ènìyàn tí nwọ́n jẹ́ ti ọba Bẹ́njámínì, tó bẹ̃ tí ọba Bẹ́njámínì ní àlãfíà títí ní gbogbo ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó ní ọmọ mẹ́ta; ó sì pe orúkọ nwọn ní Mòsíà, Hẹ́lórómù àti Hẹ́lámánì. Ó sì mú kí a kọ́ wọn ní gbogbo èdè àwọn bàbá rẹ̀, wípé nípasẹ̀ èyí nwọn yíò di onímọ̀ ènìyàn; àti pé kí nwọn lè mọ̀ nípa àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ tí a ti sọ láti ẹnu àwọn bàbá nwọn, tí a fi lé nwọn lọ́wọ́ nípa ọwọ́ Olúwa. Òun sì tún kọ́ wọn nípa àwọn ìwé ìrántí èyítí a fín sí ara àwọn àwo idẹ, ó sì wí báyĩ: Ẹ̀yin ọmọ mi, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin rántí pé bíkòbáṣe ti àwọn àwo wọ̀nyí, tí wọn ní àwọn ìwé ìrántí àti àwọn òfin wọ̀nyí nínú nwọn, àwa ìbá ti jìyà nínú àìmọ̀, bẹ̃ni títí di lọ́wọ́lọ́wọ́ yĩ, láìní ìmọ̀ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ti Ọlọ́run. Nítorítí kò bá ṣeéṣe fún bàbã wa, Léhì, kí ó rántí gbogbo ohun wọ̀nyí, láti fi nwọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, bíkòṣe nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ti àwọn àwo wọ̀nyí; nítorí tí a ti kọ́ ọ ní èdè àwọn ará Égíptì, nítorí-èyi òun lè ka àwọn òfin wọ̀nyí, kí ó sì fi nwọn kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, pé nípa báyĩ, nwọn yíò lè kọ́ àwọn ọmọ nwọn, nwọn yíò sì mú awọn òfin Ọlọ́run ṣẹ, tí ó fi di ìgbà lọ́wọ́lọ́wọ́ yĩ. Mo wí fún nyín, ẹ̀yin ọmọ mi, bíkòbáṣe nítorí àwọn nkan wọ̀nyí, tí a ti fi pamọ́ tí a sì tọ́jú nípa ọwọ́ Ọlọ́run, kí àwa lè kà kí ó sì yé wa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ rẹ̀, kí a sì ní àwọn òfin rẹ̀ ní iwájú wa nígbà-gbogbo, pé àwọn bàbá wa pãpã ìbá ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́, àwa ìbá sì ti ri bí àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì, tí wọn kò mọ́ ohunkóhun nípa àwọn nkan wọ̀nyí, tí wọn kò sì tún gbà wọ́n gbọ́ nígbàtí a fi nwọ́n kọ́ nwọn, nítorí àṣà ti àwọn bàbá nwọn, tí kò pé. A! ẹ̀yin ọmọ mi, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin rántí pé àwọn ọ̀rọ̀ nwọ̀nyí jẹ́ òtítọ́, àti pé àwọn ìwé ìrántí wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́. Ẹ kíyèsĩ, àwọn àwo ti Nífáì pẹ̀lú, tí ó ní àwọn ìwé ìrántí àti àwọn ọ̀rọ̀ àwọn bàbá wa láti ìgbà tí wọ́n ti jádekúrò ní Jerúsálẹ́mù títí di ìsisìyí, nwọ́n sì jẹ́ òtítọ́; àwa sì lè mọ̀ nípa ìdánilójú nwọn nítorítí a ní nwọ́n níwájú wa. Àti nísisìyí, ẹ̀yin ọmọ mi, èmi fẹ́ kí ẹ rántí láti ṣe àyẹ̀wò nwọn lẹ́sọ̀lẹsọ̀, kí ẹ̀yin lè ṣe ànfãní nípa èyí; èmi sì fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè ṣe rere ní orí ilẹ̀ nã, gẹ́gẹ́bí àwọn ìlérí tí Olúwa ti ṣe fún àwọn bàbá wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun míràn ni ọba Bẹ́njámínì sì kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, èyítí a kò kọ sínú ìwé yĩ. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí ọba Bẹ́njámínì ti dẹ́kun kíkọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì darúgbó, ó sì ríi pé òun fẹ́rẹ̀ lọ sí ibi tí gbogbo ará nlọ; nítorí-èyi, ó gbèrò pé ó tọ́ láti fi ìjọba fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀. Nítorí-èyi, ó ní kí a mú Mòsíà wá sí iwájú òun; àwọn wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún un, wípé: Ọmọ mi, èmi fẹ́ kí o ṣe ìkéde jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ yĩ ní ãrin àwọn ènìyàn yĩ, tàbí àwọn ará Sarahẹ́múlà, àti àwọn ará Mòsíà ti nwọn ngbé inú ilẹ̀ nã, nípa èyítí nwọn ó péjọpọ̀; nítorípé ní ọ̀la, èmi yíò kéde fún àwọn ènìyàn mi wọ̀nyí láti ẹnu èmi tìkara mi pé ìwọ ni ọba àti olórí àwọn ènìyàn yí, ẹnítí Olúwa Ọlọ́run wa ti fún wa. Àti pẹ̀lú, èmi yíò fún àwọn ènìyàn yí ní orúkọ kan, pé tí a ó fi yà nwọ́n sọ́tọ̀ lórí gbogbo ènìyàn tí Olúwa Ọlọ́run ti mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù; èmi sì ṣe èyí nítorípé wọ́n ti jẹ́ onítara ènìyàn nípa pípa awọn òfin Olúwa mọ́. Èmi sì fún nwọn ní orúkọ kan tí a kò lè parẹ́ láéláé, bíkòṣe nípa ìrékọjá. Bẹ̃ni, à t i pãpã mo wí fún nyín, wípé tí àwọn ènìyàn Olúwa tí a ṣe ojúrere sí wọ̀nyí bá ṣubú sínú ìrékọjá, tí nwọ́n sì di ìkà àti alágbèrè ènìyàn, pé Olúwa yíò jọ̀wọ́ nwọn, nípa èyí tí wọn ó di aláìlágbára gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin wọn; òun kò sì ní pa nwọn mọ́, nípa agbára rẹ̀ nlá aláìlẹ́gbẹ́, bí ó ti ṣe pa àwọn bàbá wa mọ́ di ìsisìyí. Nítorítí èmi wí fún ọ, pé tí kò bá ṣe pé ó na apá rẹ̀ fún ìpamọ́ àwọn bàbá wa, nwọ́n ìbá ti ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Lámánì, nwọ́n ìbá sì ti di ẹni ìpalára sí ìkórira wọn. Ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí ọba Bẹ́njámínì parí ọ̀rọ̀ rẹ ní sísọ fún ọmọ rẹ̀, ni ó sì fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ìjọba nã. Àti pẹ̀lú, ó fún un ní àṣẹ lórí ìwé ìrántí èyítí a fín sórí àwọn àwo idẹ; àti sórí àwọn àwo ti Nífáì; àti bákannã idà Lábánì, àti lórí ìṣù tàbí afọ̀nàhàn, èyítí ó mú àwọn bàbà wa la aginjù já, èyítí a pèsè láti ọwọ́ Olúwa wípé nípa rẹ̀, a ó ṣe amọ̀nà nwọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí ó ṣe ṣe àkíyèsí àti ìtara èyítí a fún un. Nítorí-èyi, bí nwọ́n ṣe ṣe àìṣọ́tọ́ nwọ́n kùnà láti ṣe rere àti láti lọ síwájú nínú ìrìnàjò nwọn, ṣùgbọ́n a lé nwọn padà, nwọ́n sì fa ìbínú Ọlọ́run sórí nwọn; nítorí-èyi a fi ìyàn àti ìpọ́njú gidigidi bá nwọn jà, kí ó lè rú nwọn sókè ní ìrántí iṣẹ́ nwọn. Àti nísisìyí, ó sì ṣe tí Mòsíà kọjá lọ, tí ó sì ṣe gẹ́gẹ́bí bàbárẹ̀ ti pàṣẹ fún un, tí ó sì kéde sí gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, pé nípa bẹ̃ nwọn o kó ara nwọn jọ pọ̀, láti gòkè lọ sí tẹ́mpìlì láti gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ tí bàbá rẹ̀ níláti bá nwọn sọ. 2 Ọba Bẹ́njámínì bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀—Ó tún sọ nípa ti ìṣòtítọ́, àìṣègbè, àti ìjọba rẹ̀ pẹ̀lú ohun tí ẹ̀mí—Ó gbà nwọ́n nímọ̀ràn wípé kí nwọ́n sin Ọba wọn ti Òkè-ọ̀run—Àwọn tí nwọ́n tàpá sí Ọlọ́run yíò ṣe àròkàn bĩ ti iná àjọ́kú ni ìwọ̀n ọdun 124 ki a to bi Oluwa wa. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí Mòsíà ti ṣe gẹ́gẹ́bí bàbá rẹ̀ ti paláṣẹ fún un, tí ó sì ti ṣe ìkéde jákè-jádò ilẹ̀ nã, tí àwọn ènìyàn nã sì kó ara nwọn jọ jákè-jádò ilẹ̀ nã, kí nwọn kí ó lè gòkè lọ sí tẹ́mpìlì láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí ọba Bẹ́njámínì yíò bá nwọn sọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó sì wà níbẹ̀ tóbẹ̃ tí nwọn kò kà nwọ́n; nítorítí nwọ́n ti bí sĩ púpọ̀púpọ̀, nwọ́n sì ti di alágbára ní ilẹ̀ nã. Nwọ́n sì tún mú nínú àwọn àkọ́bí àwọn agbo ẹran nwọn, kí nwọn kí ó lè rú ẹbọ àti ọrẹ-ẹbọ sísun gẹ́gẹ́bí òfin Mósè; Àti pẹ̀lú kí nwọ́n kí ó lè fi ọpẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run nwọn, ẹnití ó ti mú nwọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, àti ẹnití ó ti gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, tí ó sì ti yan àwọn ẹnití ó tọ́, láti jẹ́ olùkọ́ nwọn, àti ẹnití ó tọ́ láti jẹ́ ọba nwọn, ẹnití ó ti fi àlãfíà lélẹ̀ ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti ẹnití ó ti kọ́ nwọn láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí nwọ́n kí ó lè yọ̀, kí nwọ́n sì kún fún ìfẹ́ sí Ọlọ́run àti sí gbogbo ènìyàn . Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n gòkè wá sí inú tẹ́mpìlì, nwọ́n pa àgọ́ nwọn yíká kiri, ọkùnrin kọ̣́kan gẹ́gẹ́bí ìdílé rẹ̀, èyítí ó jẹ́ ìyàwó, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọkùnrin nwọn, àti àwọn ọmọbìnrin nwọn, bẹ̀rẹ̀ láti èyítí ó dàgbà jùlọ, títí dé èyítí ó kéré jùlọ, ẹbí kọ̣́kan sì wà lọ́tọ̀. Nwọ́n sì pàgọ́ nwọn yí tẹ́mpìlì ká, olúkúlùkù sì ṣe ilẹ̀kùn rẹ̀ kí ó kọjú sí tẹ́mpìlì, pé nípa bẹ̃, nwọn ó wà nínú àgọ́ nwọn, nwọn ó sì máa gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ tí Bẹ́njámínì ọba yíò bá nwọn sọ; Nítorítí àwọn ènìyàn nã pọ̀ púpọ̀ tóbẹ̃ tí ọba Bẹ́njámínì kò lè kọ́ nwọn ní ohun gbogbo nínú tẹ́mpìlì, nítorí-èyi, ó pàṣẹ fún kíkọ́ ilé ìṣọnà, pé nípa bẹ̃ èyítí àwọn ènìyàn rẹ̀ yíò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tí yíò bá nwọn sọ. Ó sì ṣe tí ó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ láti inú ilé ìṣọnà nã; gbogbo nwọn kò sì lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorípé àwọn ènìyàn nã pọ̀ púpọ̀; nítorí-èyi ó pàṣẹ pé kí a kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí òun sọ ránṣẹ́ sí ãrin àwọn tí nwọn kò sí ní agbègbè ìgbọ́ ohùn rẹ̀, kí àwọn nã lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ, tí ó sì pàṣẹ pé kí nwọ́n kọ, wípé: Ẹ̀yin arákùnrin mi, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti péjọpọ̀, ẹ̀yin tí ẹ lè gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ mi tí èmi yíò bá yín sọ ní òní; nítorítí èmi kò pàṣẹ pé kí ẹ gòkè wá láti ṣe àìkàsí ohun tí èmi yíò bã yín sọ, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó gbọ́ tèmi, kí ẹ ṣí etí yín, kí ẹ̀yin lè gbọ́, àti ọkàn yin kíẹ̀yin lè ní òye, àti inú yín, kí ohùn ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lè di kedere ní iwájú yin. Èmi kò pàṣẹ fún nyín pé kí ẹ jáde wá kí ẹ lè bẹ̀rù mi tàbí kí ẹ̀yin kí ó rò wípé èmi fúnra mi ju ẹlẹ́ran ara lọ. Ṣùgbọ́n èmi dàbí yin, ẹ̀nití onírũrú àìlera nínú ara àti ẹ̀mí lè bẹ̀wò; síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn yĩ ti yàn mí, bàbá mi sì ti yà mí sọ́tọ̀, a sì gbà fún un nípa ọwọ́ Olúwa, wípé kí èmi kí ó jẹ́ olórí àti ọba lórí ènìyàn yĩ; a sì ti fi mí sí ìtọ́jú àti ìpamọ́ nípa agbára àìlẹ́gbẹ́ rẹ̀, láti sìn yín pẹ̀lú gbogbo agbára, iyè àti ipá ti Olúwa ti fún mi. Mo wí fún yin wípé bí a ti gbà fún mi pé kí èmi kí ó lo ọjọ́ mi ní ṣíṣe iṣẹ́-ìsìn fún nyín, àní, títí di àkokò yĩ, tí èmi kò sì bèrè wúrà tàbí fàdákà tàbí irúkirú ọrọ̀ lọ́wọ́ yin; Bẹ̃ni èmi kò gbà kí a sé yín mọ́ inú túbú, tàbí pé kí ẹ̀yin kí ó ṣe ara nyín bí ẹrú, tàbí kí ẹ̀yin kí ó pànìyàn, tàbí ṣe ìgárá, tàbí jalè, tàbí ṣe panṣágà; bẹ̃ni, èmi kò gbà kí ẹ hu ìwà ìkà, mo sì ti kọ yin pé kí ẹ pa awọn òfin Olúwa mọ́, nínú ohun gbogbo èyítí ó ti pàṣẹ fún un nyin— Bẹ̃ sì ni èmi, tikarami, ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ mi, pé kí èmi lè ṣe iṣẹ́-ìsìn fún yín, àti pé kí a ma di ẹrú owó-orí lé yin, àti pé kí ohunkóhun kí ó máṣe dé bá yín èyítí ó bá ni nínú jẹ́—àti nínú gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí tí èmi ti sọ, ẹ̀yin fúnra yín jẹ́ ẹlẹ́rĩ lóni. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò ṣe gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí fún ìgbéraga, bẹ̃ni èmi kò sọ àwọn nkan wọ̀nyí sí ipa pé kí ẹ̀yin kí ó lè fi nyín sùn; ṣùgbọ́n èmi sọ nwọ́n fún nyín kí ẹ̀yin lè mọ̀ wípé mo lè dáhùn sí ẹ̀rí ọkàn ti o mọ́ yéké níwájú Ọlọ́run lóni. Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yin pé nítorípé èmi sọ fún nyín wípé mo ti lo ọjọ́ mi ní iṣẹ́-ìsìn yín, èmi kò ní lọ́kàn láti gbéraga, nítorípé nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run ni èmi sã ti wà. Ẹ sì kíyèsĩ, mo sọ àwọn nkan wọ̀nyí fún nyín pé kí ẹ̀yin lè kọ́ ọgbọ́n; kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ wípé bí ẹ̀yin bá wà nínú iṣẹ́-ìsìn arákùnrin yín, inú iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run nyín ni ẹ̀yin ṣã wà. Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti pè mí l’ọ́ba yín; njẹ́ bí èmi, tí ẹ̀ npè ní ọba yin, bá nṣiṣẹ́ lati sìn nyín, kò ha yẹ kí ẹ ṣiṣẹ́ láti sin ara yín? Ẹ kíyèsĩ pẹ̀lú, tí èmi, tí ẹ̀ npè ní ọba yín, tí ó ti lo ọjọ́ rẹ̀ ní inú iṣẹ́-ìsìn yín, tí mo sì tún wà nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run, bá ní ẹ̀tọ́ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ láti ọwọ́ yín, A! báwo ni ẹ̀yin ìbá ṣe dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọba òkè-ọ̀run yín tó ! Mo wí fún yín, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé tí ẹ̀yin bá fi gbogbo ọpẹ́ àti ìyìn tí gbogbo ẹ̀mí nyìn ni, fún Ọlọ́run nã ẹnití ó dáa yín, tí ó sì ti pa yín mọ́, tí ó sì dá nyín sí, tí ó sì ti mú kí inú nyín dùn, tí ó sì ti gbà kí ẹ̀yin jọ gbé pọ̀ pẹ̀lú ara yín ní àlãfí— Mo wí fún nyín pé bí ẹ̀yin bá sin ẹni tí ó dá nyín láti ìbẹ̀rẹ̀, tí ó sì npa yín mọ́ láti ọjọ́ dé ọjọ́, nípa fífún yín ní ẽmí, pé kí ẹ̀yin lè wà lãyè, kí ẹ sì rìn, kí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú yín, tí ó sì nràn yín lọ́wọ́ láti ìgbà kan dé òmíràn—mo wípé, bí ẹ̀yin bá lè sìn ín pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí yín, síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀yin yíò jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ aláìlérè. Ẹ kíyèsĩ, gbogbo ohun tí ó bẽrè lọ́wọ́ yín ni pé kí ẹ pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́; òun sì ti ṣèlérí fún yín pé tí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, ẹ̀yin yíò ṣe rere ní ilẹ̀ nã; Òun kò sì nyípadà kúrò ní èyí tí ó ti sọ; nítorí-èyi, bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, òun yíò bùkún fún yín, yíò sì mú kí ẹ ṣe rere. Àti nísisìyí, ní àkọ́kọ́, Òun ti dáa yín, ó sì ti fún yín ní ẹ̀mí nyín, èyítí ẹ̀yin jẹ ẹ́ ní gbèsè lé lórí. Ní ọ̀nà kejì, ó fẹ́ kí ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́bí Òun ti pàṣẹ fún un yín; èyí tí ó jẹ́ wípé tí ẹ̀yin bá ṣe, Òun máa bùkún fún y í n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀; àti nítorí-èyi, Òun ti san án fún yín. Ẹ̀yin ṣì tún jẹẹ́ ní gbèsè, ẹ̀yin yíò sì jẹẹ́ títí laélaé; nítorí-èyi, kíni ẹ̀yin ní i ẹ nlérí? Àti nísisìyí, èmi bẽrè, njẹ́ ẹ̀yin lè sọ ohun kankan fúnra yín? Èmi dáhùn, Rárá. Ẹ̀yin kò lè sọ pé ẹ̀yin pọ̀ to erùpẹ̀ ilẹ̀; bẹ̃ sì ni a dá nyín láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ti ẹnití ó da nyín nií ṣe. Àti Èmi, èmi pẹ̀lú, tí ẹ pè ní ọba yín, èmi kò sàn ju ẹ̀yin tìkara yín lọ; nítorípé erùpẹ̀ ni èmi nã. Ẹ̀yin sì kíyèsĩ pé èmi ti darúgbó, mo sì ti fẹ́rẹ̀ bọ́ ara yĩ jù sílẹ̀ fún ilẹ. Nítorí-èyi, gẹ́gẹ́bí mo ṣe wí fún un yín wípé èmi ti sìn yín, tí èmi nrìn pẹ̀lú ọkàn tí ó mọ́ níwájú Ọlọ́run, tó bẹ̃ tí èmi ní ìgbà yí láti jẹ́ kí ẹ̀yin péjọ, kí èmi kí ó lè wà láìlẹ́bi, kí ẹ̀jẹ̀ yín máṣe wá sórí mi, nígbàtí èmí yíò bá dúró láti gba ìdájọ́ Ọlọ́run lórí ti àwọn ohun èyítí ó tí pàṣẹ fún mi nípa yín. Mo wí fún nyín pé èmi ti jẹ́ kí ẹ̀yin péjọ pọ̀ kí èmi kí ó lè fọ aṣọ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ yín; ní àkokò yĩ tí èmi ti fẹ́rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ìsà òkú mi, pé kí èmi lè lọ ní àlãfíà, kí ẹ̀mí àìkú mi lè lọ darapọ̀ mọ́ àwọn akọrin lókè ní kíkọ́ orin ìyìn sí Ọlọ́run tí ó tọ́. Àti pẹ̀lú-pẹ̀lù, mo wí fún un yín wípé mo ti mú kí ẹ̀yin kó ara yín jọ pọ̀, kí èmi lè kéde fún nyín pé èmi kò lè jẹ́ olùkọ́ nyín, tàbí ọba nyín mọ́; Nítorípé ní àkokò yíi pãpã, gbogbo ará mi wárìrì púpọ̀púpọ̀ nígbàtí èmi ngbìyànjú láti bá nyín sọ̀rọ̀; ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ndì mí mú, ó sì ti gbà fún mi láti bá yín sọ̀rọ̀, ó sì ti pã láṣẹ fún mi kí èmi kéde fún yín lonĩ, wípé Mòsíà ọmọ mi ni ọba àti alakoso lórí yín. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin mãṣe bí ẹ̀yin ti íṣe látẹ̀hìnwá. Bí ẹ̀yin ṣe pa àwọn òfin mi mọ́, àti àwọn òfin bàbá mi nã, tí ẹ sì ṣe rere, tí a sì ti pa nyín mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nyín, bákannã bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin ọmọ mi mọ́, tàbí òfin Ọlọ́run èyítí a o fi fún yín nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin yíò ṣe rere ní ilẹ̀ nã, àwọn ọ̀tá nyín kò sì ní lágbára lórí nyín. Ṣùgbọ́n, A! ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ ṣọ́ra bí bẹ̃kọ́, èdèàìyedè yíò dìde lãrín yín, ẹ̀yin yíò sì ṣe ìfẹ́ ẹ̀mí ibi nã, èyítí bàbá mi Mòsíà sọ nípa rẹ̀. Ẹ kíyèsĩ, a ti fi ègún gún lórí ẹnìkẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ ẹ̀mí nã; nítorítí bí ó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀, tí ó wà bẹ̃ tí ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyĩyí ni ó mu ègbé sórí ẹ̀mí ara rẹ̀; nítorítí ó ti gba èrè ìyà títí ayé,nítorípé ó rékọjá sí òfin Ọlọ́run ní ìlòdì si ìmọ̀ èyítí ó ní. Mo wí fún yín, pé kò sí ẹnìkẹ́ni lãrín yín, àfi àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín tí a kò tĩ kọ nípa àwọn nkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n tí nwọ́n mọ̀ pé ẹ̀yin jẹ gbésẹ̀ ayérayé sí Bàbá yín ti ọ̀run, láti fún un ní gbogbo ohun tí ẹ ní àti èyítí ẹ jẹ́; a sì ti kọ́ nwọn nípa ìwé ìrántí èyítí ó ní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nínú, èyítí àwọn wòlĩ mímọ́ ti sọ, bẹ̃ni, láti ìgbà tí bàbá wa, Léhì, jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù; Àti pẹ̀lú-pẹ̀lù, gbogbo àwọn ohun tí àwọn bàbá wa ti sọ, títí di ìsisìyí. Ẹ kíyèsĩ, pẹ̀lú, nwọ́n sọ àwọn ohun tí Olúwa pa láṣẹ fún nwọn; nítorí-èyi wọ́n jẹ́ èyítí ó tọ́ àti òtítọ́. Àti nísisìyí, mo wí fún yín, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti mọ̀, tí a sì ti kọ́ọ yín ní àwọn nkan wọ̀nyí, tí ẹ̀yin bá rékọjá, tí ẹ sì ṣe ìlòdì sí àwọn ohun tí a sọ, tí ẹ̀yin fa ara yín sẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ Ẹ̀mí Olúwa, tí kò sì ní ãyè nínú yín láti tọ́ nyín sọ́nà ní ipa ọgbọ́n, pé tí ẹ lè jẹ́ alábùkún-fún, tí e ṣe rere, kí a sì pa nyín mọ́— Mo wí fún yín, wípé ẹ̀ni nã tí ó bá ṣe èyí, ni ó jáde ní ìsọ̀tẹ́ ní gbangban sí Ọlọ́run; nítorínã, ó gbà láti gbọ́ran sí ẹ̀mí ibi nã lẹ́nu, ó sì di ọ̀tá sí òdodo gbogbo; nítorínã, Olúwa kò ní ãyè nínú rẹ̀, nítorítí kò lè gbé nínú tẹ́mpìlì àìmọ́. Nítorínã, tí ẹní nã kò bá ronúpìwàdà, tí ó sì wà bẹ̃, tí ó sì kú gẹ́gẹ́bí ọ̀tá Ọlọ́run, ìbẽrè fún àìṣègbè ti Ọlọ́run yíò ta ẹ̀mí àìkú rẹ̀ jí sí ẹ́bi ara rẹ̀, tí yìó jẹ́ kí ó súnkì kúrò níwájú Olúwa, tí yíò sì kún àyà rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀bi, àti ìrora, àti àròkàn, èyítí ó dàbí iná tí a kò lè pa, èyítí ẹ̀là-iná rẹ̀ nrú sókè, títí láéláé. Àti nísisìyí mo wí fún yín, pé ãnú kò sí fún ẹni nã; nítorínã, àkóyọrí ìpín rẹ ni pé kí ó fi ara da oró tí kò nípẹ̀kun. A, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti gbó, àti ẹ̀yin ọ̀dọ́, àti ẹ̀yin ọmọ wẹ́wẹ́ tí ẹ lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yé, nítorítí èmi ti sọ̀rọ̀ ní kedere sí i yín kí ó lè yé nyín, èmi bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ lè tají sí ìràntí àwọn ipò búburú tí àwọn tí ó ti ṣubú sínú ìwàirékojá wa. Àti pẹ̀lú-pẹ̀lù, mo fẹ́ kí ẹ ro ti ipò alábùkún-fún àti ayọ̀ àwọn tí ó pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Nítorítí kíyèsĩ, nwọ́n jẹ́ alábùkún-fún nínú ohun gbogbo, ní ti ara àti ti ẹ̀mí; tí nwọ́n bá sì forítĩ ní òtítọ́ dé òpin a ó gbà nwọ́n sí ọ̀run, pé nípa èyí nã nwọn ó gbé pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ipò inúdídùn tí kò nípẹ̀kun. A! ẹ rántí, ẹ rántí pé àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́; nítorítí Olúwa Ọlọ́run ni ó ti sọọ́. 3 Ọba Bẹ́njámínì tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀—Olúwa Alèwílèṣe yíò ṣiṣẹ́ lãrín àwọn ènìyàn nínú àgọ́-ara erùpẹ̀—Ẹ̀jẹ̀ yíò jáde nínú gbogbo ojú ìlãgùn ara rẹ̀ bí ó ṣe nṣètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ayé—Orúkọ tirẹ̀ nìkan ni ipa èyítí ìgbàlà ńwá—Ènìyàn lè bọ́ ìwà ti ara sílẹ̀, kí nwọ́n sì di Àwọn Ènìyàn Mímọ́ nípasẹ̀ Ètùtù nã—Ìdálóró ẹlẹ́ṣẹ̀ yíò dàbĩ adágún iná àti imí ọjọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 124 kí a tó bí Olúwa wa. Ẹ̀wẹ̀ ẹ̀yin arákùnrin mi, èmifẹ́ kí ẹ farabalẹ̀, nítorítí mo ní ohun tí ó kù láti bá yín sọ; nítorí ẹ kíyèsĩ, mo ní ohun látí bá nyín sọ nípa èyítí ó nbọ̀wá. Àwọn ohun tí èmi yíò sọ fún yín sì jẹ́ mímọ̀ fún mi nípasẹ̀ ángẹ́lì kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó sì wí fún mi pé: Jí; èmi sì jí, sì wò o ó dúró níwájú mi. Ó sì wí fún mi pé: Jí, kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí èmi yíò sọ fún ọ; nítorí kíyèsĩ, èmi wá láti kéde ìròyìn ayọ̀ nlá nã fún ọ. Nítorítí Olúwa ti gbọ́ àdúrà rẹ, ó sì ti ṣe ìdájọ́ òdodo rẹ, ó sì ti rán mi láti kéde fún ọ kí ìwọ kí ó lè yọ̀; kí o sì lè kéde fún àwọn ènìyàn rẹ, kí àwọn nã lè kún fún ayọ̀ pẹ̀lú. Nítorí kíyèsĩ, àkokò nã yíò de, kò sì jìnà rárá, pé, pẹ̀lú agbára, Olúwa Alèwílèṣe, ẹnití ó jọba, tí ó ti wà, tí ó sì wà láti ayérayé dé ayérayé, yíò sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀run sí ãrin àwọn ọmọ ènìyàn, yíò sì gbé nínú àgọ́-ara erùpẹ̀, yíò sì jáde lọ lãrín àwọn ènìyàn, yíò sì ṣiṣẹ́ ìyanu nlá, àwọn bĩ ìwòsàn aláìsàn, jíjí òkú dìde, mímú arọ rìn, afọ́jú kí ó ríran, àti odi kí ó gbọ́ràn, àti wíwo onírũrú àrùn. Òun yíò sì lé àwọn èṣù jáde tàbí àwọn ẹ̀mí ibi tí ngbé inú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn. Ẹ sì wọ́, yíò sì faradà àdánwò, àti ìrora ara, ebi, òùngbẹ, àti ãrẹ̀, pãpã ju èyítí ènìyàn lè faradà, àfi tí yíò jẹ́ sí ipa ikú; nítorí kíyèsĩ, ẹ̀jẹ̀ sun jáde láti inú gbogbo ojú ìlãgún ara rẹ̀, títóbi sì ni àròkàn rẹ̀ fún ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra àwọn ènìyàn rẹ̀ yíò jẹ́. A ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, Bàbá ọ̀run òun ayé, Ẹlẹ́dã ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀; a ó sì pe orúkọ ìyá rẹ̀ ní Màríà. Ẹ sì wọ́, ó wá láti wá bá àwọn tirẹ̀, kí ìgbàlà lè wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ènìyàn, àní nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; àti pãpã lẹ́hìn gbogbo eleyĩ nwọn yíò kã sí ènìyàn, nwọn ó sì sọ wípé ó ní èṣù, nwọn yíò sì nã, nwọn yíò sì kàn án mọ́ àgbélèbú. Òun yíò sì dìde ní ọjọ́ kẹ́ta láti inú òkú; sì kíyèsĩ, ó dúró láti ṣe ìdájọ́ ayé; sì kíyèsĩ, a ṣe ohun gbogbo kí ìdájọ́ òdodo lè wá sórí àwọn ọmọ ènìyàn. Nítorí kíyèsĩ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí nwọ́n ti ṣubú nípasẹ̀ ìwàìrékọjá Ádámù, tí nwọ́n ti kú láìmọ ìfẹ́ Ọlọ́run nípa nwọn, tàbí tí nwọ́n ti ṣẹ̀ nínú àìmọ̀. Ṣùgbọ́n ègbé, ègbé ni fún ẹni tí ó mọ̀ wípé ó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run! Nítorítí ìgbàlà kò sí fún irú ẹni bẹ̃ àfi nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì Olúwa. Olúwa Ọlọ́run sì ti rán àwọn wòlĩ mímọ́ rẹ̀ sí ãrin gbogbo àwọn ọmọ ènìyàn, láti kéde àwọn nkan wọ̀nyí sí gbogbo ìbátan, orílẹ̀-èdè, àti ahọ́n, pé nípa báyĩ ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ pé Krístì nbọ̀, irú ẹni bẹ̃ lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, kí nwọn ó sì yọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ nlá, tí yíò sì dà bí ẹni pé ó ti dé sí ãrín nwọn. Síbẹ̀ Olúwa Ọlọ́run ríi pé àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn, ó sì gbé òfin kan kalẹ̀ fún nwọn, àní òfin Mósè. Àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì, iṣẹ́ ìyanu, oríṣiríṣi, àti òjìji, ni ó sì fi hàn nwọ́n, nípa bíbọ̀ rẹ̀; àwọn wòlĩmímọ́ nã sì bá nwọn sọ̀rọ̀ nípa bíbọ̀ rẹ̀; síbẹ̀síbẹ̀, nwọn sé ọkàn nwọn le, kò sì yé nwọn wípé òfin Mósè kò já mọ́ nkankan àfi nípasẹ̀ ètùtù ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Àti bí ó bá sì ṣeéṣe pé kí àwọn ọmọdé lè dẹ́ṣẹ̀, a kò lè gbà nwọ́n là; ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín, alábùkún-fún ni nwọ́n; nítorí kíyèsĩ, gẹ́gẹ́bí ti Ádámù, tàbí ti ara, nwọ́n ṣubú, síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀jẹ̀ Krístì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ nwọn. Àti pẹ̀lú, mo wí fún nyín, pé kì yíò sí orúkọ míràn tí a fún ni, tàbí ọ̀nà míràn, tàbí ipa èyítí ìgbàlà lè wá fún àwọn ọmọ ènìyàn, àfi nínú àti nípasẹ̀ orúkọ Krístì, Olúwa Alèwílèṣe. Nítorí kĩyesi, ó nṣe ìdájọ́, ìdájọ́ rẹ̀ sì jẹ́ èyítí ó tọ́; ọmọ-ọwọ́ kò sì lè parun èyítí ó kú ní kékeré; ṣùgbọ́n ènìyàn nmu ègbé sórí ẹ̀mí ara nwọn, bíkòṣepé nwọ́n bá rẹ ara nwọn sílẹ̀, tí nwọ́n sì dàbí ọmọdé, tí nwọ́n sì gbàgbọ́ pé ìgbàlà ti wà rí, ó sì wà, ó sì mbọ̀ wá, nínú àti nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ètùtù Krístì, Olúwa Alèwílèṣe. Nítorítí ènìà ẹlẹ́ran ara jẹ ọ̀tá Ọlọ́run, ó sì ti wà bẹ̃ láti ìgbà ìṣubú Ádámù, yíò sì wà bẹ̃ títí láéláé, bíkòṣepé ó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ònfà Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó sì gbé ìwà ti ara sílẹ̀, tí ó sì di ènìyàn mímọ́ nípasẹ̀ ètùtù Krístì Olúwa, tí ó sì dà bí ọmọdé, onítẹríba, oníwá-tútù, onírẹ̀lẹ̀, onísũrù, kíkún fún ìfẹ́, tí ó fẹ́ láti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ohun gbogbo èyítí Olúwa ríi pé ó tọ́ láti fi bẹ̃ wò, àní gẹ́gẹ́bí ọmọdé ṣe jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún bàbá rẹ̀. Àti pẹ̀lú, mo wí fún nyín, pé àkokò nã yíò dé ti ìmọ̀ nípa Olùgbàlà kan yíò tàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, ahọ́n, àti ènìyàn. Ẹ kíyèsĩ, nígbàtí àkokò nã bá dé, kò sí ẹnití yíò wà ní àìlẹ́bi níwájú Ọlọ́run, àfi ti nwọ́n bá jẹ́ àwọn ọmọdé, nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Olúwa Ọlọ́run Alèwílèṣe. Àti ní àkokò yĩ pãpã, nígbàtí ìwọ yíò ti kọ́ àwọn ènìyàn rẹ ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pa láṣẹ fún ọ, àní nígbànã ni nwọn kò ní jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Ọlọ́run, àfi gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ èyítí èmi ti bá ọ sọ. Àti nísisìyí èmi ti sọ awọn ọ̀rọ̀ èyítí Olúwa Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún mi. Báyĩ sì ni Olúwa wí: Nwọn yíò dúró gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí tí ó mọ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn yí, ní ọjọ́ ìdájọ́; nípa èyítí a ó ṣe ìdájọ́ nwọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ìbã jẹ́ dáradára, tàbí búburú. Bí nwọ́n bá sì jẹ́ búburú, a o là nwọn lójú kí nwọn lè rí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwà ìríra nwọn, èyítí ó jẹ́ kí nwọ́n sún sẹ́hìn kúrò ní iwájú Olúwa sí ipò ìbànújẹ́ àti oró àìnípẹ̀kun, nínú èyítí nwọn kò lè kúrò mọ́; nítorínã nwọn ti mu ègbé sórí ẹ̀mí ara nwọn. Nítorínã, nwọ́n ti mu nínú ago ìbínú Ọlọ́run, aiṣegbe èyítí kò lè yẹ̀ lórí nwọn bí kò ṣe yẹ̀ pé Ádámù yíò ṣubú nítorítí ó jẹ nínú èso tí a kà lẽwọ̀; nítorínã ãnú kò lè wà fún nwọn títí láé. Ìdálóró nwọn sì dà bí adágún iná àti imí ọjọ́, ẹ̀là iná èyítí a kò lè pa, àti ẽfín èyítí ó nrú sókè títí láéláé. Báyĩ ni Olúwa ti pã láṣẹ fún mi. Àmín. 4 Ọba Bẹ́njámínì tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀–Ìgbàlà wá nítorí Ètùtù nã—Gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kí a sì gbà ọ́ là–Dí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mú nípasẹ̀ ìṣòtítọ́—Fifún tálákà nínú ọ̀rọ̀ rẹ—Ṣe ohun gbogbo pẹ̀lú ọgbọ́n àti ètò. Ní ìwọ̀n ọdún 124 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ó sì ṣe ti ọba Bẹ́njámínì ti parí ọ̀rọ̀ sísọ ní ti èyítí a fún un láti ọwọ́ ángẹ́lì Olúwa, ó sì wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã yíká, sì kíyèsĩ, nwọ́n ti ṣubú lulẹ̀, nítorítí ẹ̀rù Olúwa ti wá sórí nwọn. Nwọ́n sì ti rí ara nwọn nínú ipò ara nwọn, èyítí ó kéré sí ẹrùpẹ̀ ilẹ̀. Gbogbo nwọ́n sì ké sókè pẹ̀lú ohùn kan wípé: A! ṣãnú, kí ó sì ro ti ẹ̀jẹ̀ ètùtù Krístì kí àwa lè gba ìdáríjì fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ọkàn wa sì di wíwẹ̀mọ́; nítorítí àwa gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ọ̀run òhun ayé, àti oun gbogbo; tí yíò sọ̀kalẹ̀ wá lãrín àwọn ọmọ ènìyàn. Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí nwọ́n ti sọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Ẹ̀mí Olúwa sọ̀kalẹ̀ sórí nwọn, nwọ́n sì kún fún ayọ̀, nígbàtí nwọ́n ti gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, tí nwọ́n sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn, nítorí ìgbàgbọ́ tí ó tayọ tí nwọ́n ní nínú Jésù Krístì ẹniti yio wá, gẹ́gẹ́bí awọn ọ̀rọ̀ èyítí ọba Bẹ́njámínì ti bá nwọn sọ. Ọba Bẹ́njámínì sì tún la ẹnu rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá nwọn sọ̀rọ̀, wípé: Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi àti arákùnrin mi, ẹ̀yin ìbátan mi àti ènìyàn mi, èmi yíò sì tún fẹ́ kí ẹ farabalẹ̀, kí ẹ lè gbọ́, ní àgbọ́yé èyítí ó kù nínú ọ̀rọ̀ mi tí èmi yíò bã yín sọ. Nítorí kíyèsĩ, bí imọ nípa dídára Ọlọ́run ní àkokò yí bá ti ta yín jí sí ipò asán nyín, àti ipò aláìnílárí àti ìdíbàjẹ́ tí ẹ wa— Mo wí fún nyín, bí ẹ̀yin bá ti ní ìmọ̀ nípa dídára Ọlọ́run, àti ti agbára rẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́, àti ọgbọ́n rẹ̀, àti sũrù rẹ̀, àti ìpamọ́ra rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn; àti pẹ̀lú, ètùtù èyítí a ti pèsè sílẹ̀ láti ìpilẹ̀sẹ̀ ayé, wípé nípa bẹ̃ ìgbàlà lè jẹ́ ti ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi àìṣèmẹ́lẹ́ pa awọn òfin rẹ̀ mọ́, tí ó sì tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́ nã, àní títí dé òpin ayé rẹ̀, àní ayé ti ara kíkú— Mo wípé èyí ni ẹni nã tí ó gba ìgbàlà, nípasẹ̀ ètùtù nã èyítí a ti pèsè láti ìpilẹ̀sẹ̀ ayé fún gbogbo aráyé, tí nwọ́n ti wà láti ìgbà ìṣubú ti Ádámù, tàbí tí nwọ́n wà tàbí tí yíò wà, àní títí dé òpin ayé. Èyí sì ni ipa ọ̀nà ti ìgbàlà fi nwá. Kò sì sí ìgbàlà míràn bíkòṣe èyítí a ti sọ nípa rẹ̀; bẹ̃ni kò sì sí ipò míràn nípa èyítí a lè gba ènìyàn là àfi àwọn èyítí mo ti sọ fún un yín. Gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run; gbàgbọ́ pé ó wà, àti pé òun ni ó dá ohun gbogbo, ní ọ̀run àti ayé; gbàgbọ́ pé ó ní gbogbo ọgbọ́n, àti gbogbo agbára, ní ọ̀run àti ní ayé; gbàgbọ́ pé ènìyàn kò ní òye ohun gbogbo tí ó lè yé Olúwa. Àti pẹ̀lú, gbàgbọ́ pé ẹ̀yin níláti ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ nyín kí ẹ sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀, kí ẹ sì rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run; kí ẹ sì bẽrè pẹ̀lú ọkàn tọ́tọ́ pé kí ó dáríjì yín; àti nísisìyí, bí ẹ̀yin bá sì gbagbogbo nkan wọ̀nyí gbọ́, ẹ ríi pé ẹ ṣe nwọ́n. Àti pẹ̀lú mo wí fún un yín gẹ́gẹ́bí mo ti sọ síwájú, pé bí ẹ̀yin ṣe ti ní ìmọ̀ nípa ògo Ọlọ́run, tabí tí ẹ̀yin ti mọ̀ nípa dídára rẹ, tí ẹ sì ti tọ́ ìfẹ́ rẹ̀ wò, tí ẹ sì ti gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nyín, èyítí ó fún nyín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ ní ọkàn nyín, àní èmi fẹ́ kí ẹ̀yin rántí, kí ẹ sì fi ìrántí títóbi Ọlọ́run, àti ipò àìjámọ́nkankan nyín, àti dídára àti ìfaradà rẹ̀ sí yín, ẹ̀dá aláìyẹ, kí ẹ sì rẹ ara yín sílẹ̀ ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ púpọ̀, ní pípe orúkọ Olúwa lójọ́júmọ́, ní dídúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ nínú èyítí ó nbọ̀wá, èyítí a sọ nípa rẹ̀ láti ẹnu ángẹ́lì nã. Kí ẹ kíyèsĩ mo wí fún nyín pé bí ẹ̀yin bá ṣe eleyĩ, ẹ̀yin yíò máa yọ̀ nígbà-gbogbo, ẹ ó sì kún fún ìfẹ́ Ọlọ́run, ẹ ó sì ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nyín nígbà-gbogbo; ẹ̀yin yíò sì dàgbà nínú ìmọ̀ ògo ẹnití ó dáa yín, tàbí, nínú ìmọ̀ èyítí ó tọ́ àti tí ó sì jẹ́ òtítọ́. Ẹ̀yin kò sì ní ní ọkàn láti pa ara nyín lára, ṣùgbọ́n láti gbé pọ̀ ní àlãfíà, àti láti fi fún ènìyàn gbogbo gẹ́gẹ́bí ó ṣe tọ́ síi. Ẹ̀yin kò sì ní jẹ́ kí ebi kí ó pa àwọn ọmọ nyín, tàbí kí nwọ́n wà ní ìhòhò; ẹ̀yin kò sì ní jẹ́ kí nwọ́n ré òfin Ọlọ́run kọjá, kí nwọ́n ní ìjà tàbí ãwọ̀ lãrín ara nwọn, kí nwọ́n sì sin èṣù, ẹni tí ó jẹ́ olórí fún ẹ̀ṣẹ̀, tàbí tí ó jẹ́ ẹ̀mí ibi nnì tí àwọn bàbá wa ti sọ nípa rẹ̀, oun tí ó jẹ́ ọ̀tá sí gbogbo ìṣòtítọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yíò kọ́ nwọn láti rìn nípa ọ̀nà òtítọ́ àti ìwà àìrékọjá; ẹ̀yin yíò kọ́ nwọn kí nwọ́n ní ìfẹ́ àra nwọn, kí nwọ́n sì máa sin ara nwọn. Àti pẹ̀lú, ẹ̀yin tìkarayín yíò ran àwọn tí à ndánwò lọ́wọ́; ẹ̀yin yíò fún àwọn aláìní nínú ọ̀rọ̀ nyín; ẹ̀yin kò sì ní jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ alágbe já sí asán, kí ẹ sì lée jáde láti parun. Bóyá ẹ̀yin yíò wípé: Okùnrin nã ni ó mú ìyà yí wá sórí ara rẹ̀; nítorínã, èmiyíò dá ọwọ́ mi dúró, èmi kò sì ní fún un nínú oúnjẹ mi, tàbí kí èmi kí ó fún un nínú ọrọ̀ mi kí ó má bã jìyà, nítorítí ìyà rẹ jẹ́ èyítí ó tọ́— Ṣùgbọ́n èmi wí fún ọ, A! ọmọ ènìyàn, ẹnìkẹ́ni tí ó bá ṣe eleyĩ, ní ìdí pàtàkì láti ronúpìwàdà; bí kò sì ronúpìwàdà kúrò nínú èyítí ó ti ṣe, yíò parun títí láé, kò sì ní ìpín nínú ìjọba Ọlọ́run. Nítori kíyèsĩ, gbogbo wa kò ha íṣe alágbe bi? Njẹ́ a kì ha gbẹ́kẹ̀lé Ẹní nã, àní Ọlọ́run, fún gbogbo ọrọ̀ tí a ní, fún oúnjẹ àti aṣọ, àti fún wúrà, àti fún fàdákà, àti fún gbogbo dúkìá tí a ní lóríṣiríṣi? Sì Kíyèsĩ, ní àkokò yí pãpã, ẹ̀yin ti nképe orúkọ rẹ̀, tí ẹ sì nbẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín. Njẹ́ ó gbà pé kí ẹ̀bẹ̀ nyín jẹ́ lásán? Rárá; ó ti tú Ẹ̀mí rẹ̀ lé orí nyín, ò sì ti mú kí ọkàn nyín kún fún ayọ̀, ó sì ti mú kí ẹnu yín pamọ́ kí ẹ̀yin má lè rí ọ̀rọ̀ sọ, bẹ̃ ni ayọ̀ ọ yín tóbi tó. Àti nísisìyí, bí Ọlọ́run, ẹnití ó dá nyín, ẹnití ẹ̀yin gbára lé fún ẹ̀mí nyín, àti fún gbogbo ohun tí ẹ ní, àti tí ẹ jẹ́, tí ó sì fún nyín ní ohunkóhun tí ó tọ́ tí ẹ bá bẽrè, nínú ìgbàgbọ́, tí ẹ sì gbàgbọ́ pé ẹ ó ri gbà, A! njẹ́nígbànã, ó yẹ kí ẹ̀yin bá ara nyín pín nínú ọrọ̀ yín. Bí ìwọ bá sì ṣe ìdájọ́ fún ẹni nã tí o bẹ̀bẹ̀ fún ìní rẹ kí ó máa bã parun, tí ìwọ sì dáa lẹ́bi, báwo ni ìdálẹ́bi rẹ yíò ṣe jẹ́ èyítí ó tọ́ tó fún ìháwọ́ ohun-ìní rẹ, èyítí kĩ ṣe tìrẹ, bíkòṣe ti Ọlọ́run, ẹni tí ẹ̀mí rẹ jẹ́ pẹ̀lú; àti síbẹ̀ ìwọ kò bẹ̀bẹ̀, tàbí ronúpìwàdà fún àwọn ohun tí ìwọ ti ṣe. Mo wí fún ọ, ègbé ni fún ẹni nã, nítorítí ohun-ìní rẹ̀ yíò parun pẹ̀lú rẹ̀; àti nísisìyí, èmi sì sọ ohun wọ̀nyí fún àwọn tí nwọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ nípa ohun ti ayé yĩ. Àti pẹ̀lú, èmi wí fún àwọn tálákà, ẹ̀yin tí ẹ kò ní, ṣùgbọ́n síbẹ̀ tí ẹ ní ànító pé kí ẹ gbé ayé láti ọjọ́ dé ọjọ́; mo sọ wípé gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kọ aláìní nnì, nítorítí ẹ̀yin kò ní; èmi ìbá fẹ́ kí ẹ wí nínú ọkàn nyín pé: èmi kò fifúnni nítorítí èmi kò ní, ṣùgbọ́n bí mo bá ní, èmi yíò fifúnni. Àti nísisìyí, bí ẹ̀yin bá sọ eleyĩ nínú ọkàn nyín, ẹ̀yin wà ní àìlẹ́ṣẹ̀, bíkòjẹ́bẹ̃, a dá nyín lẹ́bi; ìdálẹ́bi rẹ sì tọ́ nítorítí ìwọ ṣe ojúkòkúrò sí èyítí ìwọ kò ì tĩ gbà. Àti nísisìyí, nítorí àwọn ohun wọ̀nyí tí èmi ti bá nyín sọ—àní, nítorí gbígba ìdáríjì-ẹ̀ṣẹ̀ nyín lójojúmọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè rìn láìlẹ́ṣẹ̀ níwájú Ọlọ́run—èmi ìbá fẹ́ kí ẹ fi nínú ohun-ìní nyín fún àwọn tálákà, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí èyítí ó ní, gẹ́gẹ́bí bíbọ́ àwọn tí ebi npa, dídá aṣọ bò àwọn tí ó wà ní ìhòhò, bíbẹ àwọn aláìsàn wò, àti pípèsè fún ìtura nwọn, nípa ti ẹ̀mí àti ara, gẹ́gẹ́bí àìní nwọn. Kí ẹ̀yin sì ríi pé ẹ ṣe àwọn nkan wọ̀nyí ní ipa ọgbọ́n àti ètò; nítorípé kò tọ́ kí ènìyàn sáré ju bí ó ṣe lágbára. Àti pẹ̀lú, ó jẹ́ ohun ẹ̀tọ́ pé kí ó lãpọn, kí ó bã lè gba èrè nã; nítorínã, a níláti ṣe ohun gbogbo létò-letò. Èmi ìbá sì fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí pé ẹnìkẹ́ni nínú nyín tí ó bá yá ohun kan lọ́wọ́ aládũgbò rẹ níláti dá ohun nã padà tí ó yá, gẹ́gẹ́bí ó ti ṣẹ àdéhùn, àìjẹ́bẹ̃, ìwọ ti dẹ́ṣẹ̀; bóyá ìwọ yíò sì jẹ́ kí aládũgbò rẹ dẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú. Àti lakotan, èmi kò lè sọ gbogbo ohun tí ó lè jẹ́ kí ẹ dẹ́ṣẹ̀; nítorípé onírurú ọ̀nà àti ipá ni ó wà, nwọ́n pọ̀ tóbẹ̃, tí èmi kò lè kà nwọ́n. Ṣùgbọ́n mo lè sọ èyí fún un yín, pé bí ẹ kò bá kíyèsĩ ara nyín, àti èrò ọkàn nyín, àti ọ̀rọ̀ sísọ yín, àti iṣẹ́ nyín, kí ẹ sì pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí ẹ sì tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́ nínú èyítí ẹ̀yin tí gbọ́ nípa bíbọ̀wá Olúwa, àní títí dé òpin ayé nyín, ẹ̀yin yíò parun. Àti nísisìyí, A! ọmọ ènìyàn, rántí, má sì parun. 5 Àwọn Ènìyàn Mímọ́ di ọmọ Krístì nípasẹ̀ ìgbàgbọ́—A sì nfi orúkọ Krístì pè nwọ́n—Ọba Bẹ́njámínì gbà nwọ́n níyànjú kí nwọ́n ní ìtẹramọ́ àti ìdúróṣinṣin nínú iṣẹ́ rere. Ní ìwọ̀n ọdún 124 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ó sì ṣe nígbàtí ọba Bẹ́njámínì sì ti bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ báyĩ, ó ránṣẹ́ lãrín nwọn, kí ó lè mọ̀ bóyá àwọn ènìyàn rẹ̀ gba àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti bá nwọn sọ gbọ́. Gbogbo nwọn sì kígbe lóhùn kan, wípé: Bẹ̃ni, àwa gba gbogbo ọ̀rọ̀ tí ìwọ ti bá wa sọ gbọ́; àwa sì mọ̀ nípa ìdánilójú àti òtítọ́ nwọn, nítorí Ẹ̀mí Olúwa Alèwílèṣe, tí ó ti mú ìyípadà nlá bá wa, tàbí nínú ọkàn wa, tí àwa kò sì ní ẹ̀mí àti ṣe búburú mọ́, ṣùgbọ́n láti máa ṣe rere títí. Àti àwa tìkarawa, pẹ̀lú, nípa dídára àìníye Ọlọ́run, àti ìfihàn Ẹ̀mí rẹ, ní òye nlá nípa èyítí nbọ̀ wá; tí ó bá sì tọ́, àwa lè ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ohun gbogbo. Ìgbàgbọ́ tí àwa sì ti ní nínú ohun tí ọba wa sọ fún wa ni ó mú wa ní ìmọ̀ nlá yĩ, nípa èyí tí àwa nyọ̀ pẹ̀lú irú ayọ̀ nlá bẹ̃. Àwa sì fẹ́ láti dúró lórí májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run wa láti ṣe ìfẹ́ rẹ, àti láti ṣe ìgbọ́ran sí àwọn òfin rẹ̀ nínú ohun gbogbo tí yíò paláṣẹ fún wa, ní gbogbo ìyókù ayé wa, kí àwa kí ó má bã mú oró tí kò nípẹ̀kun bá ara wa, gẹ́gẹ́bí ángẹ́lì nã ti sọ, kí àwa máṣe mu nínú ago ìbínú Ọlọ́run. Àti nísisìyí àwọn wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ tí ọba Bẹ́njámínì fẹ́ kí nwọ́n sọ; nítorínã ó wí fún wọn pé: Ẹ̀yin ti sọ ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́; májẹ̀mú tí ẹ̀yin sì ti dá jẹ́ májẹ̀mú òtítọ́. Àti nísisìyí, nítorí májẹ̀mú tí ẹ̀yin sì ti dá a ó máa pè yín ní ọmọ Krístì, ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin, àti ọmọ rẹ̀ lóbìnrin; nítorí ẹ kíyèsĩ, ní òní yí ni ó ti bí nyín nínú ẹ̀mí; nítorítí ẹ̀yin wípé ọkàn nyín ti yípadà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; nítorínã, a bí nyín nínú rẹ ẹ̀yin sì ti di ọmọ rẹ̀ l’ọ́kùnrin àti l’óbìnrin. Àti ní abẹ́ orí yĩ ni ẹ̀yin ti di òmìnira, kò sì sí orí míràn nípasẹ̀ èyítí a lè sọ yín di òmìnira. Kò sí orúkọ míràn tí a fún ni nípasẹ̀ èyítí ìgbàlà yíò wá; nítorínã, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ gbé orúkọ Krístì lé oríi yín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run kí ẹ̀yin kí ó lè ṣe ìgbọ́ran títí dé òpin ayé nyín. Yíò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe eleyĩ ni a ó bá ní ọwọ́ ọ̀tun Ọlọ́run, nítorítí òun yíò mọ orúkọ nã tí à fi npè é; nítorítí a ó fi orúkọ Krístì pè é. Àti nísisìyí yíò sì ṣe, ẹnìkẹni tí kò bá gbé orúkọ Krístì ka orí ara rẹ̀, ni a ó fi orúkọ míràn pè; nítorínã, yíò bá ara rẹ̀ ní ọwọ́ òsì Ọlọ́run. Èmi ìbá sì fẹ́ kí ẹ̀yin ó rántí pẹ̀lú, pé èyí ni orúkọ tí èmi wípé èmi yíò fún un yín èyítí kò ní parẹ́ láéláé, bíkòṣe nípasẹ̀ ìrékọjá; nítorínã, ẹ ṣọ́ra kí ẹ̀yin kí ó máṣe rékọjá, kí orúkọ nã má ṣe parẹ́ kúrò l’ọ́kàn nyín. Mo wí fún nyín, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ rántí láti mú orúkọ nã dúró ní kíkọ lé oókan àyà nyín nígbà-gbogbo, kí a má bã bá a yín ní ọwọ́ òsì Ọlọ́run, ṣùgbọ́n pé kí ẹ gbọ́ kí ẹ sì mọ ohùn ìpè nã èyítí a ó fi pè nyín, àti pẹ̀lú, orúkọ nã èyítí yíò pè yín. Nítorí báwo ni ènìyàn yíò ṣe mọ Olúwa rẹ̀, èyítí kò tĩ sìn, tí ó sì jẹ́ àjòjì síi, tí ó sì jìnà sí èrò àti ète ọkàn rẹ̀? Àti pẹ̀lú, njẹ́ ènìyàn lè mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí íṣe ti aladugbo rẹ̀, kí ó fi pamọ́? Mo wí fún nyín, Rárá; kò tilẹ̀ ní jẹ́ kí ó jẹ nínú agbo rẹ̀, ṣùgbọ́n yíò lé e, yíò sì sọ ọ́ sóde. Mo wí fún nyín, wípé bẹ̃ ni yíò rí lãrín yín bí ẹ̀yin kò bá mọ́ orúkọ èyítí à fi npè yín. Nítorínã, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó ní ìtẹramọ́ àti ìdúróṣinṣin,kí ẹ kúnfún iṣẹ́ rere nígbà-gbogbo, kí Krístì, Olúwa Ọlọ́run Alèwílèṣe, lè fi èdìdí dì yín mọ́ra rẹ̀, kí a lè mú u yín wá sí ọ̀run, kí ẹ̀yin lè ní ìgbàlà àìlópin àti ìyè àìnípẹ̀kun, nípasẹ̀ ọgbọ́n, àti agbára, àti àiṣègbè, àti ãnú rẹ̀, ẹnití ó dá ohun gbogbo, ní ọ̀run òun ayé, tí ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ga jù ohun gbogbo lọ. Àmín. 6 Ọba Bẹ́njámínì kọ àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ènìyàn o sì yan àwọn àlùfã láti kọ́ nwọn—Mòsíà ṣe ìjọba gẹ́gẹ́bí ọba olódodo. Ní ìwọ̀n ọdún 124 sí 121 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ọba Bẹ́njámínì sì rò wípé ó tọ́, lẹ́hìn tí ó ti bá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀ tán, pé kí ó kọ àkọsílẹ̀ orúkọ gbogbo àwọn tí nwọ́n ti wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run láti pa awọn òfin rẹ̀ mọ́. Ó sì ṣe tí kò sí ẹnìkan, àfi àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, tí kò tĩ wọ inú májẹ̀mú nã àti tí kò gba orúkọ Krístì sí ara nwọn. Ó sì tún ṣe nígbàtí ọba Bẹ́njámínì ti parí gbogbo nkan wọ̀nyí, tí ó sì ti ya Mòsíà ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti jẹ́ olórí àti ọba lórí àwọn ènìyàn rẹ̀, tí ó sì ti fún un ní gbogbo ọ̀rọ̀ ìyànjú nípa ti ìjọba nã, tí ó sì ti yan àwọn àlùfã lati kọ́ àwọn ènìyàn nã, pé nípa bẹ̃ nwọ́n lè gbọ́ kí nwọ́n sì mọ àwọn òfin Ọlọ́run, àti láti ta nwọ́n jí sí ìrántí ìbúra ti nwọn ti ṣe, ó tú àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã ká, nwọ́n sì padà, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí ìdílé nwọn, lọ sí ilé nwọn. Mòsíà sì bẹ̀rẹ̀sí í jọba dípò bàbá rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀sí í jọba ní ọmọ ọgbọ̀n ọdún, tí ó sì mú gbogbo àkokò nã jẹ́ ìwọ̀n bĩ irínwó ọdún lé mẹ́rindínlọ́gọ̀rin láti àkokò tí Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Ọba Bẹ́njámínì sì gbé ọdún mẹ́ta síi, ó sì kú. Ó sì ṣe tí ọba Mòsíà rìn ní ọ̀nà Olúwa, ó sì ṣe àkíyèsí ìdájọ́ àti ìlànà rẹ̀, ó sì pa awọn òfin rẹ̀ mọ́ nínú ohun gbogbo tí ó pa láṣẹ fún un. Ọba Mòsíà sì pàṣẹ pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀ mã dá’ko, òun nã, fúnrarẹ̀, dá’ko, pé nípa bẹ̃ kò ní ni àwọn ènìyàn rẹ̀ lára, kí ó lè ṣe gẹ́gẹ́bí èyítí bàbá rẹ̀ ti ṣe nínú ohun gbogbo. Kò sì sí asọ̀ lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún mẹ́ta. 7 Ámọ́nì ṣe àwárí ilẹ̀ àwọn Léhì-Nífáì, níbití Límháì ti jẹ́ ọba—Àwọn ará Límháì wà nínú oko-ẹrú àwọn ará Lámánì—Límháì sọ ìtàn ìgbésí ayé nwọn—Wòlĩ kan (Ábínádì) ti jẹ́ ẹ̀rí pé Krístì ni Ọlọ́run àti Bàbá ohun gbogbo—Àwọn tí nwọ́n nfúrúgbìn ẹ̀gbin yíò kórè ãjà, àwọn tí nwọ́n bá sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa ni a ó kó yọ. Ní ìwọ̀n ọdún 121 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ọba Mòsíà ti ní àlãfíà títí fún ìwọ̀n ọdún mẹ́ta, ó wũ kí ó mọ̀ nípa àwọn ènìyàn nã tí nwọ́n kọjá lọ láti gbé ilẹ̀ àwọn Léhì-Nífáì, tàbí ní ìlú nlá ti Léhì-Nífáì; nítorítí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò gburo nwọn láti ìgbàtí nwọ́n ti kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; nítorínã, nwọ́n dã lágara pẹ̀lú ìyọlẹ́nu nwọn. Ó sì ṣe tí ọba Mòsíà gbà pé kí mẹ́rìndínlógún nínú àwọn ọkùnrin alágbára nwọn kọjá lọ sí ilẹ̀ Léhì-Nífáì, láti lọ ṣe ìwádĩ nípa àwọn arákùnrin nwọn. Ó sì ṣe pé, ní ọjọ́ kejì, tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí gòkè lọ, nwọ́n sì mú ẹnìkan tí à npè ní Ámọ́nì lọ́wọ́, nítorítí ó jẹ́ alágbára àti ènìyàn títóbi, àti ọmọ Sarahẹ́múlà; ó sì tún jẹ́ aṣãjú nwọn. Àti nísisìyí, nwọn kò mọ ọ̀nà tí nwọn ìbá gbà nínú aginjù kí nwọ́n lè lọ sí ilẹ̀ àwọn Léhì-Nífáì; nítorínã nwọn rìn kiri fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ nínú aginjù, àní fún ogójì ọjọ́ ni nwọ́n fi rìn kiri. Nígbàtí nwọ́n sì ti rìn kiri fún ogójì ọjọ́, nwọ́n dé ibi òkè kan, tí ó wà ní apá àríwá sí ilẹ̀ ti Ṣílómù, níbẹ̀ ni nwọ́n sì pàgọ́ nwọn sí. Ámọ́nì sì mú mẹ́ta nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, orúkọ nwọn sì ni Ámálẹ́kì, Hẹ́lẹ́mù, àti Hẹ́mù, nwọ́n sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ilẹ̀ ti Nífáì. Sì kíyèsĩ, nwọ́n bá ọba àwọn ènìyàn nã tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Nífáì àti ní ilẹ̀ ti Ṣílómù pàdé; àwọn ìṣọ́ ọba sì yí nwọn ká, nwọ́n sì mú nwọn, nwọ́n sì dì nwọ́n, nwọ́n sì gbé nwọn sọ sínú túbú. Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n ti wà nínú túbú fún ọjọ́ méjì, a sì tún mú nwọn wá síwájú ọba, a sì tú ìdè nwọn; nwọ́n sì dúró níwájú ọba, a sì gbà nwọ́n lãyè, tàbí kí a wípé pã láṣẹ, pé kí nwọ́n dáhùn àwọn ìbẽrè tí òun yíò bí nwọ́n. Ó sì wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, èmi ni Límháì, ọmọ Nóà, tí ó jẹ́ ọmọ Sẹ́nífù, tí ó jáde kúrò nínú ilẹ̀ ti Sarahẹ́múlà láti jogún ilẹ̀ yĩ, tí ó jẹ́ ilẹ̀ bàbá nwọn, tí a fi ṣe ọba gẹ́gẹ́bí ohùn àwọn ènìyàn nã. Àti nísisìyí, èmi fẹ́ láti mọ́ ìdí èyítí ẹ̀yin ṣe ní ìgboyà tó bẹ̃gẹ̃ tí ẹ fi wá sí itòsí odi ìlú yĩ, nígbàtí èmi, tìkarã, mi wà pẹ̀lú àwọn ìṣọ́ mi ní ẹnu ọ̀nà òde? Àti nísisìyí, fún ìdí èyí ni èmi ṣe jẹ́ kí a dá a yín sí, kí èmi kí o lè ṣe ìwádĩ lẹ́nu yín, bí bẹ̃ kọ́, èmi ìbá ti ní kí àwọn ìṣọ́ mi pa yín. A gbà yín lãyè pé kí ẹ sọ̀rọ̀. Àti nísisìyí, nígbàtí Ámọ́nì ríi pé a gba òun lãyè láti sọ̀rọ̀, ó jáde síwájú, ó sì tẹríba níwájú ọba; ó sì tún dìde, ó wípé: Á! ọba, èmi dúpẹ́ níwájú Ọlọ́run ní ọjọ́ òní yíi pé mo ṣì wà lãyè, tí a sì gbà mí lãyè láti sọ̀rọ̀; èmi yíò sì gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà; Nítorítí ó dá mi lójú pé tí ìwọ bá ti mọ̀ mí ìwọ kò ní gbà kí èmi kí ó wọ àwọn ìdè wọ̀nyí. Nítorípé èmi ni Ámọ́nì, èmi sì jẹ́ ọmọ Sarahẹ́múlà, èmi sì ti jáde wá láti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà láti ṣe ìwádĩ nípa àwọn arákùnrin wa, ti Sẹ́nífù mú jáde wá kúrò nínú ilẹ̀ nã. Àti nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn tí Límháì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ámọ́nì, inú rẹ̀ dùn lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì wípé: Nísisìyí, mo mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé, àwọn arákùnrin mi ti nwọn wà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà sì wà lãyè. Àti nísisìyí èmi yíò ṣe àjọyọ̀; àti ní ọ̀la, èmi yíò mú kí àwọn ènìyàn mi nã ṣẹ àjọyọ̀ pẹ̀lú. Nítorí kíyèsĩ, àwa wà ní oko-ẹrú àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì nmú wa sìn ní ọ̀nà tí ó burú jùlọ láti faradà. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, àwọn arákùnrin wa yíò gbà wá kúrò nínú oko ẹrú nã, tàbí kí a wípé, kúrò l’ọ́wọ́ àwọnará Lámánì, àwa yíò sì di ẹrú nwọn; nítorítí ó sàn fún wa kí àwa kí ó jẹ́ ẹrú àwọn ará Nífáì ju pé kí àwa kí ó san owó-òde fún ọba àwọn ará Lámánì. Àti nísisìyí, ọba Límháì pàṣẹ fún àwọn ìṣọ́ rẹ pé kí nwọ́n máṣe de Ámọ́nì tàbí àwọn arákùnrin rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n kí nwọ́n lọ sí òkè nã, tí ó wà ní ìhà àríwá Ṣílómù, kí nwọ́n sì mú àwọn arákùnrin nwọ́n wá sínú ìlú nã, pé nípa bẹ̃ nwọn yíò lè jẹun, kí nwọn sì mumi, kí nwọ́n sì simi ara nwọn kúrò nínú wàhálà ìrìnàjò nwọn; nítorítí nwọ́n jìyà ohun púpọ̀; nwọ́n ti jìyà fún ebi, òùngbẹ, àti ãrẹ̀. Àti nísisìyí, ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, tí ọba Límháì ṣe ìkéde lãrín gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀, pé nípa èyí nwọn yíò péjọ pọ̀ sí inú tẹ́mpìlì, láti gbọ́ ọ̀rọ̀ èyítí yíò bá nwọn sọ. Ó sì ṣe, nígbàtí nwọ́n ti péjọ, ó sì bá nwọn sọ̀rọ̀ báyĩ, wípé: Á! ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé órí nyín sókè, kí a sì tù nyín nínú; nítorí kíyèsĩ, àkokò nã ti dé tán, tàbí kí a wípé kò jìnà, tí àwa kò ní foríbalẹ̀ fún àwọn ọ̀tá wa mọ́, l’áìṣírò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyàjú wa ni ó ti já sí asán; síbẹ̀síbẹ̀, èmi gbàgbọ́ wípé ìyànjú tí ó kù fún wa láti ṣe yíò jẹ́ aláìtàsé. Nítorínã, ẹ gbé orí nyín sókè, kí ẹ sì yọ̀, kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, nínú Ọlọ́run nnì tí íṣe Ọlọ́run Ábráhámù, àti Ísãkì, àti Jákọ́bù; àti pẹ̀lú, Ọlọ́run nnì tí ó mú àwọn ọmọ Ísráẹ́lì jáde kúrò nínú ilẹ̀ Égíptì, tí ó sì mú nwọn la Òkun Pupa kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ, tí ó sì bọ́ nwọn pẹ̀lú mánà kí nwọ́n má bã parun nínú aginjù; òun sì tún ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun fún nwọn síi. Àti pẹ̀lú, Ọlọ́run kan nã ni ó ti mú àwọn bàbá wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, tí ó sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ títí di àkokò yíi; ẹ sì kíyèsĩ; ó mú wa wá sínú oko-ẹrú yíi nítorí ìwà àìṣedẽdé àti ìwà ìríra wa. Gbogbo nyín sì ni ẹlẹ́rĩ ní ọjọ́ òní, tí Sẹ́nífù, ẹnití a fi ṣe ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹnití ó ní ìtara tí ó tayọ láti jogún ilẹ̀ àwọn bàbá rẹ, nípasẹ̀ èyítí, a sì tàn an jẹ nípa ọgbọ́n àrékérekè ọba Lámánì, ẹni tí ó ṣe àdéhùn pẹ̀lú ọba Sẹ́nífù, tí ó sì ti yọ̣́da apákan ilẹ̀ nã, tàbí kí a wípé ìlú nlá tí Léhì-Nífáì, àti ìlú nlá ti Ṣílómù; àti gbogbo ìlú tí ó wà ní agbègbè wọn— Gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí ni ó sì ṣe, fún ìdí kanṣoṣo láti mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ìrẹ̀sílẹ̀ tàbí sínú oko-ẹrú. Ẹ sì kíyèsĩ, àwa, ní àkokò yí, nsan owó-òde fún ọba àwọn ará Lámánì, èyí tí ó tó ìwọ̀n ìdásíméjì ọkà wa, àti bàbà wa, àti gbogbo wóró irúgbìn wa ní onírurú, àti ìdásíméjì gbogbo ọ̀wọ́ ẹran àti agbo-ẹran wa; àti pẹ̀lú ìdásíméjì gbogbo ohun tí a ní tàbí kí a wípé ohun ìní wa, ni ọba àwọn Lámánì lọ́gbà lọ́wọ́ wa, bí kò jẹ́ bẹ̃ òun ó gba ẹ̀mí wa. Àti nísisìyí, njẹ́ èyí kò ha ṣòro láti faradà? Njẹ́ ìpọ́njú wa yĩ kò ha pọ̀ bí? Ẹ kíyèsĩ nísisìyí, èrèdí tí àwa fi nkẹ́dùn ọkàn ni èyí. Bẹ̃ni, mo wí fún nyín, èrèdí tí àwa fi nkẹ́dùn ọkàn pọ̀ púpọ̀; nítorí melo nínú àwọn arákùnrin wa tí a ti pa, tí a ti ta ẹ̀jẹ̀ nwọnsílẹ̀ lórí asán, gbogbo ohun wọ̀nyí rí bẹ̃ nítorí ìwà àìṣedẽdé. Nítorípé bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò bá tĩ ṣubú sínú ìwàìrékọjá, Olúwa kìbá ti yọ̣́da kí ibi yĩ wá sórí nwọn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, nwọn kò ní fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n ìjà bẹ́ sílẹ̀ lãrín nwọn, tóbẹ̃gẹ̃ tí nwọn ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ lãrín ara nwọn. Nwọ́n sì ti pa wòlĩ Olúwa, bẹ̃ni, ẹni yíyàn Ọlọ́run, tí ó sọ fún wọn nípa ìwà búburú àti ẹ̀gbin nwọn, tí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí nbọ̀wá, bẹ̃ni, àní bíbọ̀ Krístì. Àti nítorípé ó sọ fún nwọn pé Krístì ni Ọlọ́run nã, Bàbá ohun gbogbo, tí ó sì sọ wípé yíò farahàn ní àwòrán ènìyàn, yíò sì jẹ́ àwòrán ìrú èyítí a fi dá ènìyàn ní àtètèkọ́ṣe; tàbí kí a sọ́ ní ọ̀nà míràn, ó wípé a dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọ́run, àti pé Ọlọ́run yíò sọ̀kalẹ̀ sí ãrin àwọn ọmọ ènìyàn, yíò sì gbé ẹ̀ran ara àti ẹ̀jẹ̀ wọ̀, yíò sí lọ kiri ní ojú àgbáyé— Àti nísisìyí, nítorítí ó sọ eleyĩ, nwọ́n pa á; ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun míràn ni nwọ́n sì ṣe, èyítí ó mú ìbínú Ọlọ́run wá sórí nwọn. Nítorínã, tani ó nyàlẹ́nu pé nwọ́n wà ní oko-ẹrú, àti pé a nfi ìpọ́njú púpọ̀ bẹ̀ wọ́n wò? Nítorí ẹ kíyèsĩ, Olúwa ti wípé: Èmi kò ní ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn mi ní ọjọ́ ìwàìrékọjá nwọn; ṣùgbọ́n èmi yíò ṣe ìdènà nwọn kí nwọn kí ó má ṣe ṣe rere; kí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ nwọn yíò sì jẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ níwájú nwọn. Àti pẹ̀lú, ò wípé: Bí àwọn ènìyàn mi bá fúrúgbìn ẹ̀gbin nwọn yíò kórè ìyàngbò rẹ̀ nínú ãjà; èrè rẹ̀ sì ni májèlé. Àti pẹ̀lú, ò wípé: Bí àwọn ènìyàn mi bá fúrúgbìn ẹ̀gbin, nwọn yíò kórè ìjì láti apá ìlà oòrùn, tí ó mú ìparun wá lọ́gán. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, ìlérí Olúwa ti di ìmúṣẹ, a sì kọlũ nyín, a sì pọ́n nyín lójú. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá lè yí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú èrò ọkàn yín ní kíkún kí ẹ̀yin sì gbẹ́kẹ̀ nyín lé e, kí ẹ sì sìn ín pẹ̀lú ìtara ọkàn nyín, bí ẹ̀yin bá ṣe èyí, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú rẹ, yíò gbà yín kúrò nínú oko-ẹrú. 8 Ámọ́nì nkọ́ àwọn ará Límháì—Ó gbọ́ nípa àwọn àkọsílẹ̀ mẹ́rìnlélógún ti Járẹ́dì—Àwọn aríran lè ṣe ìtumọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ ti àtijọ́—Kò sí ẹ̀bùn tí ó tayọ ti aríran. Ní ìwọ̀n ọdún 121 kí a tó bí Olúwa wa. Ósì ṣe pé lẹ́hìn tí ọba Límháì ti dẹ́kun ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorítí ó sọ ohun púpọ̀ fún nwọn, díẹ̀ nínú nwọn ni èmi sì kọ sínú ìwé yĩ, ó sì sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ohun gbogbo nípa àwọn arákùnrin nwọn tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Ó sì mú kí Ámọ́nì kí ó dìde níwájú àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, kí ó sì sọ gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn arákùnrin nwọn láti ìgbà tí Sẹ́nífù ti lọ jáde kúrò ní ilẹ̀ nã, àní títí di ìgbà tí òun nã ti jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã. Ó sì tún sọ fún wọn àwọn ọ̀rọ̀ ìkẹhìn tí ọba Bẹ́njámínì ti kọ́ nwọn, ó sì ṣe àlàyé nwọn fúnàwọn ènìyàn ọba Límháì, kí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó sọ lè yé nwọn. Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí ó ti ṣe gbogbo eleyĩ, ni ọba Límháì tú àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã ká, tí ó sì mú kí olúkúlùkù padà lọ sí ilé rẹ. Ó sì ṣe tí ó mú kí a gbé àwọn àwo àkọsílẹ̀ nã tí ó ní ìkọsílẹ̀ ti àwọn ènìyàn rẹ láti ìgbà tí nwọ́n ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, wá sí iwájú Ámọ́nì, kí òun lè kà nwọ́n. Nísisìyí, ní kété tí Ámọ́nì ti ka àkọsílẹ̀ nã tán, ọba nã wádĩ lọ́wọ́ rẹ̀ láti mọ̀ bóyá ó lè túmọ̀ èdè, Ámọ́nì sì sọ fún un pé òun kò lè ṣe é. Ọba s ì wí f ú n un p é : Nítorípé èmi kẹ́dùn fún ìjìyà àwọn ènìyàn mi, mo mú kí ogójì àti mẹ́ta nínú àwọn ènìyàn mi mú ìrìnàjò pọ̀n lọ sínú aginjù, pé nípa bẹ̃ nwọ́n lè ṣe àwárí ilẹ̀ ti Sarahẹ́múlà, kí àwa kí ó lè ṣípẹ̀ fún àwọn arákùnrin wa pé kí nwọ́n tú wa sílẹ̀ nínú oko-ẹrú. Nwọ́n sì sọnù nínú aginjù fún ìwọ̀n ọjọ́ pípẹ́, síbẹ̀ nwọ́n ní ãpọn, tí nwọn kò sì rí ilẹ̀ ti Sarahẹ́múlà, nwọ́n padà sí ilẹ̀ yí, tí nwọ́n ti rin ìrìnàjò nínú ilú kan tí ó wà lãrín omi púpọ̀, tí nwọ́n sì ṣe àwárí ilú kan tí ó kún fún àwọn egungun àwọn ènìyàn, àti ti ẹranko, àti ti àwọn ilé tí ó ti dí ahoro, ní ónírurú, tí nwọ́n sì ṣe àwárí ilú kan tí ènìyàn ti tẹ̀dó rí, tí nwọ́n sì pọ̀ bí àwọn ọmọ ogun Ísráẹ́lì. Àti fún ẹ̀rí pé àwọn ohun tí nwọ́n ti sọ jẹ́ ọ̀títọ́, nwọ́n mú àwo àkọsílẹ̀ mẹ́rìnlélógún bọ̀, tí nwọ́n kún fún àwọn fífín, tí nwọ́n sì jẹ́ ti ojúlówó wúrà. Ẹ sì kíyèsĩ, pẹ̀lú, nwọ́n mú àwọn ìgbàyà-ogun, tí nwọ́n tóbi, tí nwọ́n sì jẹ́ ti idẹ àti ti bàbà, tí nwọ́n sì wà ní pípé. Àti pẹ̀lú, nwọ́n kó idà, ti ẽkù nwọ́n ti parun, tí ojú nwọn sì ti dípẹtà; kò sì sí ẹnì kan tí ó lè túmọ̀ èdè nã tàbí àwọn ohun fífín tí ó wà lára àwọn àwo nã. Nítorínã ni èmi fi wí fún ọ pé: Njẹ́ ìwọ lè ṣe ìtumọ̀? Èmi sì tún wí fún ọ: Njẹ́ ìwọ mọ́ ẹnìkẹ́ni tí ó lè ṣe ìtumọ̀? Nítorítí èmi ní ìfẹ́ pé kí a túmọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí sí èdè wa; nítorípé, bóyá, nwọn ó fún wa ní ìmọ̀ ìyókù àwọn ènìyàn nã tí nwọ́n ti parun, ní ibití àkọsílẹ̀ wọ̀nyí ti wá; tàbí, bóyá nwọn ó fún wa ní ìmọ̀ nípa àwọn ènìà wọ̀nyí tí nwọ́n ti parun; èmi sì ní ìfẹ́ láti mọ́ ohun tí ó fa ìparun fún wọn. Nísisìyí, Ámọ́nì sọ fun un: Èmi lè sọ dájúdájú fún ọ, A! ọba, nípa ọkùnrin kan tí ó lè túmọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ nã; nítorí tí ó ní ohun tí ó lè wò, tí yíò fi túmọ̀ gbogbo àkọsílẹ̀ tí nwọ́n jẹ́ ti ìgbà àtijọ́; ó sì jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àwọn nkan nã ni à npè ní olùtumọ̀, kò sì sí ẹni nã tí ó lè wo inú nwọn àfi bí a bá pã láṣẹ fún un láti wọ́, kí ó má bã wo ohun tí kò yẹ fún un, kí ó si parun. Ẹnìkẹ́ni tí a bá sì pã láṣẹ fún, pé kí ó wo inú nwọn, òun nã ni à npè ní aríran. Ẹ kíyèsĩ, ọba àwọn ènìyàn tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà ni ẹni tí a pa á láṣẹ fún kí ó ṣe àwọn nkan wọ̀nyí, tí ó sì ní ẹ̀bùn nlá yĩ láti ọwọ́ Ọlọ́run. Ọba nã sì sọ wípé aríran tóbi ju wòlĩ lọ. Ámọ́nì sì sọ wípé aríran jẹ́ olùfihàn àti wòlĩ pẹ̀lú; kò sì sí ẹ̀bùn tí ènìyàn lè ní tí ó ju èyí lọ, àfi bí ó bá ní agbára Ọlọ́run, èyítí kò sí ẹnití ó lè níi; síbẹ̀, ènìyàn lè ní agbára púpọ̀ tí a fifún un láti ọwọ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n aríran lè mọ́ nípa àwọn ohun tí ó ti kọjá, àti àwọn ohun tí ó nbọ̀wá pẹ̀lú, àti nípasẹ̀ nwọn ni a ó fi ohun gbogbo hàn, tàbí pé, ní ohun ìkọ̀kọ̀ yíò kúkú di mímọ̀, tí ohun ìpamọ́ yíò wá sí ìmọ́lẹ̀, àti àwọn ohun tí a kò mọ̀, yíò di mímọ̀ nípasẹ̀ nwọn, àti pé àwọn ohun yíò di mímọ̀ nípasẹ̀ nwọn, àwọn èyítí bíkòjẹ́ bẹ̃, a kò lè mọ̀ nwọ́n. Báyĩ, Ọlọ́run ti pèsè ọ̀nà pé, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, ènìyàn lè ṣe iṣẹ́ ìyanu nlá; nítorínã, ó jẹ́ ànfàní nlá fún àwọn ará rẹ̀. Àti nísisìyí, nígbàtí Ámọ́nì sì ti parí ọ̀rọ̀ sísọ, ọba yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, ó wípé: Láìsí àní-àní, ohun ìjìnlẹ̀ nlá ni ó wà nínú àwọn àwo wọ̀nyí àti, láìsí àní-àní, a sì ti pèsè àwọn olùtúmọ̀ wọ̀nyí fún ìfihàn gbogbo ohun ìjìnlẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn. Á!, báwo ni ìyanu iṣẹ́ Olúwa ṣe pọ̀ tó, àti pé báwo ni yíò ṣe pẹ́ tó tí ìyọ́nú rẹ̀ fi wà fún àwọn ènìyàn rẹ̀; bẹ̃ni, àti pé báwo ni ìmọ̀ àwọn ọmọ ènìyàn ṣe fọ́jú àti dití tó; nítorítí nwọn kò ní ṣe àfẹ́rí ọgbọ́n, bẹ̃ni nwọn kò sì ní ìfẹ́ pé kí ó jọba lórí nwọn! Bẹ̃ni, nwọ́n dà bí ọ̀wọ́ ẹran àìtùlójú tí ó sáko kúrò lọ́dọ̀ olùṣọ́-àgùtàn, tí nwọ́n sì túká, tí a sì lé wọn, tí àwọn ẹranko búburú sì pa nwọ́n jẹ. Àwọn Àkọsílẹ̀ Sẹ́nífù —Ìtàn nípa àwọn ènìyàn rẹ, láti ìgbà tí nwọ́n ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, títí dé ìgbà tí a fi gbà nwọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì. Èyítí a kọ sí àwọn orí 9 títí ó fi dé 22 ní àkópọ̀. 9 Sẹ́nífù darí àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn jáde kúrò ní Sarahẹ́múlà láti lọ jogún ilẹ̀ Léhì-Nífáì—Ọba àwọn ará Lámánì gbà fún nwọn láti jogún ilẹ̀ nã—Ogun bẹ́ sílẹ̀ lãrín àwọn ará Lámánì àti àwọn ènìyàn Sẹ́nífù. Ní ìwọ̀n ọdún 200 sí 187 kí a tó bí Olúwa wa. Èmi, Sẹ́nífù, tí a ti kọ́ ní gbogbo èdè àwọn ará Nífáì, àti tí mo ní ìmọ̀ nípa ilẹ̀ ti Nífáì, tàbí pé nípa ilẹ̀ akọ́jogún fún àwọn bàbá wa, àti ti a rán mi gẹ́gẹ́bí amí lãrín àwọn ará Lámánì, kí èmi kí ó lè ṣe alámí sí ohun agbára nwọn, kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa lè kọlù nwọ́n, kí ó sì pa nwọ́n run—ṣùgbọ́n nígbàtí mo rí ohun rere lãrín nwọn, èmi kò fẹ́ kí a pa nwọ́n run. Nítorínã, mo bá àwọn arákùnrin mi gbèrò nínú aginjù, nítorítí èmi fẹ́ kí olórí wa bá nwọn ṣe ìpinnu; ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ ènìyàn tí ó rorò, tí ó sì ní ìfẹ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ó pàṣẹ pé kí a pa mí; ṣùgbọ́n a gbà mí là nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ tí a ta sílẹ̀; nítorítí bàbá bá bàbá jà, arákùnrin sì bá arákùnrin jà, títí dé ìgbà ti púpọ̀ nínú àwọn ọmọ ogun wa parun nínú aginjù; a sì padà,àwa tí nwọn kò pa, lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, kí a lè ròhìn nã fún àwọn ìyàwó nwọn àti àwọn ọmọ nwọn. Síbẹ̀síbẹ̀, bí èmi ti ní ìtara tí ó tayọ láti jogún ilẹ̀ àwọn bàbá wa, mo sì ṣe àkójọ gbogbo àwọn tí nwọ́n ní ìfẹ́ láti gòkè lọ láti ní ilẹ nã ní ìní, a sì tún bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wa lọ sínú aginjù kí a lè kọjá lọ sínú ilẹ̀ nã; ṣùgbọ́n, a fi ìyàn bẹ̀ wá wò, pẹ̀lú ìjìyà tí ó pọ̀ púpọ̀; nítorítí àwa lọ́ra láti rántí Olúwa Ọlọ́run wa. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, lẹ́hìn ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rìn kiri nínú aginjù, a pagọ́ sí ibi tí nwọ́n ti pa àwọn arákùnrin wa, èyítí ó sún mọ́ ilẹ̀ àwọn bàbá wa. Ó sì ṣe tí èmi tún lọ pẹ̀lú mẹ́rin nínú àwọn ará mi sínú ìlú nlá nã, tí mo tọ ọba lọ, kí èmi lè mọ́ èrò ọkàn ọba nã, àti kí èmi lè mọ̀ bóyá mo lè lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi, kí a sì jogún ilẹ̀ nã ní ìrọ̀rùn. Mo sì wọlé tọ ọba lọ, òun sì bá mi dá májẹ̀mú pé èmi lè ní ilẹ̀ ti Léhì-Nífáì ní ìní, àti ilẹ̀ ti Ṣílómù. Òun sì pàṣẹ pẹ̀lú pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã, èmi àti àwọn ènìyàn mi sì lọ sínú ilẹ̀ nã, kí àwa lè nĩ ní ìní. Àwa sì bẹ̀rẹ̀sí kọ́ àwọn ilé, a sì tún àwọn ògiri ilú nã kọ́, bẹ̃ni, àní àwọn ògiri ìlú ti Léhì-Nífáì, àti ti Ṣílómù. Àwa sì bẹ̀rẹ̀sí ro oko, bẹ̃ni, àní pẹ̀lú onírurú èso, pẹ̀lú èso àlìkámà, àti ti ọkà, àti pẹ̀lú bãlì, àti pẹ̀lú neasi, àti pẹ̀lú seumu, àti pẹ̀lú àwọn oríṣiríṣi èso míràn; àwa sì bẹ̀rẹ̀sí bí síi, àwa sì nṣe rere lórí ilẹ̀ nã. Nísisìyí, ó jẹ́ ọ̀nà ọgbọ́n àrekérekè fún ọba Lámánì, láti mú àwọn ènìyàn mi wá sí oko-ẹrú, ni ó ṣe jọ̀wọ́ ilẹ̀ nã pé kí àwa fi nĩ ni ìní. Nítorínã, ó sì ṣe, nígbàtí àwa ti tẹ ilẹ̀ nã dó fún ìwọ̀n ọdún méjìlá, tí ara ọba Lámánì bẹ̀rẹ̀sí wà ní àìrọrùn, pé ní ọ̀nà-kọnà, kí àwọn ènìyàn mi má lọ di alágbára ní orí ilẹ̀ nã, tí nwọn kò sì ní lè borí nwọn, kí nwọ́n sì mú nwọn wá sí óko-ẹrú. Nísisìyí, nwọ́n jẹ́ ọ̀lẹ àti abọ̀rìṣà ènìyàn; nítorínã nwọ́n fẹ́ láti mú wa wá sí oko-ẹrú, kí nwọ́n lè máa jẹ́ àjẹkì nínú èrè iṣẹ́ ọwọ́ wa; bẹ̃ni, kí nwọ́n lè máa bọ́ ara nwọn pẹ̀lú àwọn agbo-ẹran inú pápá wa. Nítorínã, ó sì ṣe tí ọba Lámánì bẹ̀rẹ̀sí rú àwọn ènìyàn rẹ̀ sókè kí nwọ́n lè bá àwọn ènìyàn mi jà; nítorínã ogun àti ìjà bẹ̀rẹ̀sí bẹ́ sílẹ̀ ní ilẹ̀ nã. Nítorí, ní ọdún kẹtàlá ìjọba mi ni ilẹ̀ ti Nífáì, ní ìhà gúsù ilẹ̀ Ṣílómù, nígbàtí àwọn ènìyàn nfún àwọn agbo ẹran nwọn lómi, tí nwọ́n sì nbọ́ nwọn, tí nwọ́n sì nro oko nwọn, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì kọ lu nwọ́n, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí npa nwọ́n, nwọ́n sì nkó àwọn agbo-ẹran nwọn, àti ọkà inú oko nwọn. Bẹ̃ni, ó sì ṣe tí nwọ́n sálọ, gbogbo àwọn tí nwọn kò lè bá, àní lọ sí inú ilú nlá Nífáì, nwọ́n sì ké pè mí fún ãbò. Ó sì ṣe, tí mo di ìhámọ́ra ogun fún wọn pẹ̀lú ọrún, àti ọfà, pẹ̀lú idà, ati pẹlu símẹ́tà àti pẹ̀lú kùmọ̀, àti pẹ̀lú kànnà-kànnà, àti pẹ̀lú onírurú ohun ìjà èyí tía lè ṣe, èmi àti àwọn ènìyàn mi si jáde tọ àwọn ará Lámánì lọ ní ogun. Bẹ̃ni, nínú agbára Olúwa ni àwa fi jáde lọ láti kọjú ìjà sí àwọn ará Lámánì; nítorítí èmi àti àwọn ènìyàn mi ké rara pe Olúwa kí ó lè gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, nítorítí a ta wá jí sí ìrántí àkóyọ àwọn bàbá wa. Ọlọ́run sì gbọ́ igbe wa, ó sì dáhùn àdúrà wa; àwa sì jáde lọ nínú agbára rẹ̀; bẹ̃ni, àwa lọ kọlũ àwọn ará Lámánì, ní ọjọ́ kan àti òru kan ni àwa pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ogójì àti mẹ́ta; àwa sì pa nwọ́n, títí àwa fi lé nwọn jáde kúrò ní ilẹ̀ wa. Èmi, tìkalára mi, pẹ̀lú ọwọ́ mi, sì ṣe ìrànlọ́wọ́ láti gbé àwọn òkú nwọn sin, sì kíyèsĩ; sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora-ọkàn àti ìpohùn-réré ẹkún wa, igba àti ãdọ́rin àti mẹ́sán nínú àwọn arákùnrin wa ni nwọ́n pa. 10 Ọba Lámánì kú—Àwọn ènìyàn rẹ ya jàndùkú àti ìpánle ènìyàn, nwọ́n sì gbàgbọ́ nínú ayédèrú àṣà—Sẹ́nífù àti àwọn ènìyàn rẹ̀ borí nwọn. Ní ìwọ̀n ọdún 187 sí 160 kí a tó bí Olúwa wa. Ósì ṣe tí àwa tún bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìjọba nã, àwa sì bẹ̀rẹ̀sí ní ilẹ̀ nã ní ìní àlãfíà. Mo sì mú kí àwa ṣe àwọn ohun ìjà ogun ní onírurú, pé nípa bẹ̃ èmi yíò ní àwọn ohun ìjà fún àwọn ènìyàn mi di ìgbà tí àwọn ará Lámánì yíò tún tọ̀ wá wá láti bá àwọn ènìyàn mi jagun. Mo sì fi àwọn olùṣọ́ yí gbogbo ilẹ̀ nã ká, kí àwọn ará Lámánì máa bà tún lè kọ lù wá láìfura, kí nwọ́n sì pa wá run; bẹ̃ sì ni èmi dãbò bò àwọn ènìyàn mi, àti àwọn agbo-ẹran mi, tí mo sì pa nwọ́n mọ́ kúrò nínú ìṣubú sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá wa. Ó sì ṣe tí àwa jogún ilẹ̀ àwọn bàbá wa fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, bẹ̃ni, fún ìwọ̀n ogun ọdún àti méjì. Mo sì mú kí àwọn ọkùnrin máa roko, kí nwọ́n sì gbin onírurú wóró, pẹ̀lú onírurú èso lóríṣiríṣi. Mo sì mú kí àwọn obìnrin máa hun aṣọ kí nwọ́n sì ṣe lãlã, kí nwọ́n sì ṣiṣẹ́, kí nwọ́n sì hun aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó dára, bẹ̃ni ati oríṣiríṣi aṣọ, kí àwa lè fi aṣọ bò ìhọ́hò wa; báyĩ, àwa sí ṣe rere lórí ilẹ̀ nã—báyĩ àwa sì ní àlãfíà títí ní ilẹ̀ nã fún ìwọ̀n ogún ọdún àti méjì. Ó sì ṣe tí ọba Lámánì kú, ọmọ rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀sí jọba dípò rẹ. Òun sì bẹ̀rẹ̀sí ní rú àwọn ènìyàn rẹ̀ sókè ní ìṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ènìyàn mi; nítorínã nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí gbáradì fún ogun, àti láti gòkè wá láti bá àwọn ènìyàn mi jagun. Ṣùgbọ́n èmi ti rán àwọn alámí mi jáde kákiri gbogbo ilẹ̀ Ṣẹ́múlónì, kí èmi kí ó lè ṣe àwárí ìgbáradì nwọn, kí èmi kí ó lè ṣọ́ra de nwọn, kí nwọn kí ó má bã kọlũ àwọn ènìyàn mi, kí nwọ́n sì pa nwọ́n run. Ó sì ṣe tí nwọ́n lọ sí apá àríwá ilẹ̀ Ṣílómù, pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun nwọn, àwọn ọkùnrin tí nwọ́n gbáradì pẹ̀lú ọrun àti pẹ̀lú ọfà, àti idà, ati pẹ̀lú símẹ́tà, àti òkúta, àti kànnà-kànnà; nwọ́n sì fá orí nwọn tí nwọn wàláìbò; nwọ́n sì sán àmùrè awọ yíká ìbàdí nwọn. Ó sì ṣe, tí mo mú kí àwọn obìnrin àti ọmọdé nínú àwọn ènìyàn mi fi ara pamọ́ nínú aginjù; èmi sì mú kí gbogbo àwọn arúgbó tí nwọ́n lè lo ohun ìjà, àti gbogbo àwọn ọ̀dọ́ okùnrin mi tí nwọ́n lè lo ohun ìjà, péjọ láti lọ dojúkọ àwọn ará Lámánì ní ogun; èmi sì tò nwọ́n lọ́wọ̣́wọ́, gbogbo nwọn gẹ́gẹ́bí ọjọ́ orí nwọn. Ó sì ṣe, tí àwa lọ dojú ìjà kọ àwọn ará Lámánì; tí èmi, àní èmi, ní ọjọ́ ogbó mi, lọ fún ìdojú ìjà kọ àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe, tí àwa lọ jagun nínú agbára Olúwa. Nísisìyí, àwọn ará Lámánì kò mọ́ ohunkóhun nípa Olúwa, tàbí nípa agbára Olúwa, nítorínã nwọ́n gbẹ́kẹ̀lé agbára nwọn. Síbẹ̀síbẹ̀, nwọ́n jẹ́ alágbára ènìyàn, nípa ti agbára ọmọ-ènìyàn. Nwọ́n sì jẹ́ janduku àti ìpánle ènìyàn, tí òngbẹ ẹ̀jẹ̀ ngbẹ, tí nwọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú àṣà àwọn bàbá nwọn, èyí tí ó jẹ́ báyĩ—Níní ìgbàgbọ́ pé a lé nwọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù nítorí àìṣedẽdé àwọn bàbá nwọn, àti pé àwọn arákùnrin nwọn ṣẹ̀ nwọn nínú aginjù, nwọ́n sì tún ṣẹ̀ nwọn nígbàtí nwọ́n nla òkun kọjá; Àti pẹ̀lú, pé a ṣẹ̀ nwọn nígbàtí nwọ́n wà ní ilẹ̀ ogún nwọn àkọ́kọ́, lẹ́hìn tí nwọ́n ti la òkun kọjá, gbogbo èyí nítorípé Nífáì jẹ́ olódodo nípa pípa òfin Olúwa mọ́—nítorínã ó rí ojúrere Olúwa, nítórítí Olúwa gbọ àdúrà rẹ̀, ó sì dáhùn nwọn, ó sì ṣe aṣãjú nwọn ní ìrìnàjò nwọn nínú aginjù. Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì nṣe ìbínú rẹ̀ nítorípé ìṣe Olúwa kò yé nwọn; nwọ́n tún ṣe ìbínú rẹ̀ lórí omi nítorítí nwọ́n sé àyà nwọn le sí Olúwa. Àti pẹ̀lú, nwọ́n ṣe ìbínú rẹ̀ nígbàtí nwọ́n ti dé ilẹ̀ ìlérí nã, nítorípé nwọ́n ní ó ti gba ìdarí àwọn ènìyàn nã kúrò lọ́wọ́ nwọn; nwọ́n sì lépa láti pípa á. Àti pẹ̀lú, nwọ́n ṣe ìbínú rẹ̀ nítorípé ó kọjá lọ sínú aginjù gẹ́gẹ́bí Olúwa ti pã láṣẹ fún un, ó sì gbé àwọn àkọsílẹ̀ tí a fin sórí àwọn àwo idẹ, nítorítí nwọ́n ní ó jà nwọ́n lólè. Àti báyĩ ni nwọ́n ti kọ́ àwọn ọmọ nwọn pé kí nwọ́n korira nwọn, àti pé kí nwọ́n pa nwọ́n, kí nwọ́n sì jà nwọ́n lólè àti kí nwọ́n kó nwọn, kí nwọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí nwọ́n lè ṣe láti pa nwọ́n run; nítorínã, nwọ́n ní ikorira ayérayé fún àwọn ọmọ Nífáì. Nítorí ìdí èyí ni ọba Lámánì, nípa ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, àti ìpurọ́ rẹ̀, àti ìlérí mèremère, ṣe tàn mí, tí èmi sì mú àwọn ènìyàn mi wọ̀nyí jáde wá sínú ilẹ̀ yí, kí nwọn le pa nwọ́n run; bẹ̃ni, àwa sì ti jìyà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún wọ̀nyí ní ilẹ̀ nã. Àti nísisìyí èmi, Sẹ́nífù, lẹ́hìn tí mo ti sọ gbogbo ohun wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn mi nípa àwọn ará Lámánì, mo ta nwọ́n jí láti lọ sí ójú ogun pẹ̀lú agbára nwọn ní fífi ìgbẹ́kẹ̀lé nwọn sí Olúwa; nítorínã, àwa bá nwọn jà, ní ojú kojú. Ó sì ṣe, tí àwa tún lé nwọn jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa; a sì panwọ́n ní ìpakúpa, àní lọ́pọ̀lọpọ̀, tí a kò kà nwọ́n. Ó sì ṣe, tí a tún padà sí ilẹ̀ tiwa, àwọn ènìyàn mi sì tún bẹ̀rẹ̀sí tọ́jú àwọn agbo-ẹran nwọn, àti láti ro ilẹ̀ nwọn. Àti nísisìyí, èmi, nítorípé mo ti darúgbó, gbé ìjọba lé ọ̀kan nínú àwọn ọmọ mi lọ́wọ́, nítorínã, n kò sọ ohun kankan mọ́. Àti kí Olúwa kí ó bùkún àwọn ènìyàn mi. Àmín. 11 Ọba Nóà jọba nínú ìwà búburú—Ó gbáyùn ùn nínú ayé ìfẹ́ kũfẹ́ pẹ̀lú àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀—Ábínádì sọtẹ́lẹ̀ pé a ó kó àwọn ènìyàn nã lẹ́rú—Ọba Nóà lépa ẹ̀mí rẹ. Ní ìwọ̀n Ọdún 160 sí 150 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Sẹ́nífù gbé ìjọba lé Nóà, tí íṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́; nítorínã Nóà bẹ̀rẹ̀ sí jọba dípò rẹ̀; òun kò sì rìn ní ọ̀nà bàbá rẹ̀. Nítorí kíyèsĩ, kò pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, ṣùgbọ́n ó rìn nípa ìfẹ́kúfẹ̃ ọkàn ara rẹ̀. Ó sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ aya àti àlè. Ó sì mú kí àwọn ènìyàn rẹ dẹ́ṣẹ̀, kí nwọ́n sì ṣe ohun ẹlẹ́gbin lójú Olúwa. Bẹ̃ni, nwọ́n sì hu ìwà àgbèrè àti onírurú ìwà búburú. Ó sì yàn nwọ́n ní ìdá marun ohun ìní nwọn fún owó-òde, àti ìdá marun wúrà nwọn, àti ti fàdákà nwọn, àti ìdá marun sífì nwọn, àti ti bàbá nwọn, àti ti idẹ nwọn, àti ti irin nwọn; àti ìdá marun ẹran àbópa nwọn; àti pẹ̀lú ìdá marun gbogbo ọkà nwọn. Gbogbo ohun wọ̀nyí ni ó sì fi bọ́ ara rẹ̀, àti àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀; àti àwọn àlùfã rẹ̀, àti àwọn aya nwọn àti àwọn àlè nwọn; báyĩ ó ti yí gbogbo ìṣe ìjọba nã padà. Nítorítí ó rẹ gbogbo àwọn àlùfã ti bàbá rẹ̀ ti yàsọ́tọ̀ sílẹ̀, ó sì ya àwọn míràn sọ́tọ rọ́pò nwọn, irú àwọn èyítí ọkàn nwọn ru sókè fún ìgbéraga. Bẹ̃ni, báyĩ sì ni a tì nwọ́n lẹ́hìn nínú ìwà ọ̀lẹ nwọn àti nínú ìwà ìbọ̀rìṣà nwọn, àti nínú ìwà àgbèrè nwọn, nípasẹ̀ owó-òde ti ọba Nóà ti yàn lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí; báyĩ ni àwọn ènìyàn nã ṣe lãlã púpọ̀púpọ̀ fún àtìlẹhìn àìṣedẽdé. Bẹ̃ni, nwọ́n sì tún di abọ̀rìṣà, nítorípé a tàn nwọ́n jẹ nípa ọ̀rọ̀ asán àti ẹ̀tàn ọba àti àwọn àlùfã; nítorítí nwọn nsọ ohun ẹ̀tàn fún nwọn. Ó sì ṣe tí ọba Nóà kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé tí ó lẹ́wà tí ó sì gbọ́rò; ó sì ṣe nwọ́n ní ọ̀ṣọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ ọnà igi èyítí ó dára àti pẹ̀lú oríṣiríṣi ohun oníyebíye, ti wúrà, ti fàdákà, ti irin, ti idẹ, ti sífì, àti ti bàbá. Òun sì kọ fún ara rẹ̀, ãfin tí ó gbọ́rò, àti ìtẹ́-ọba lãrín rẹ, gbogbo èyítí a fi igi dáradára ṣe, tí a sì ṣe ọnà si pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun oníyebíye. Ó sì tún mú kí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ṣe onírurú iṣẹ́ dáradára sí ara ògiri tẹ́mpìlì nã, pẹ̀lú igi oníyebíye, àti ti bàbá, àti ti idẹ. Àti àwọn ijoko tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn olórí àlùfã, tí nwọ́n ga ju àwọn ijoko yókù lọ, ni ó ṣe ní ọ̀ṣọ́ pẹ̀lú wúrà dídán; ó sì mú kí a kó ibi ìgbáralé síwájú nwọn, pé kí nwọ́n lè máa gbéara àti apá nwọn lée nígbàtí nwọ́n bá nsọ̀rọ̀ irọ́ àti ọ̀rọ̀ asán sí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó sì ṣe, tí ó kọ́ ilé ìṣọna kan sí itòsí tẹ́mpìlì; bẹ̃ ni, tẹ́mpìlì gíga kan, èyí tí ó ga tó bẹ̃ tí òun lè dúró lórí rẹ̀ kí ó sì rí ilẹ̀ Ṣílómù, àti ilẹ̀ Ṣẹ́múlónì, èyítí àwọn ará Lámánì ti gbà ní ìní; òun sì tún lè rí gbogbo àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní agbègbè nwọn. Ó sì ṣe, tí ó mú kí a kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé nínú ilẹ̀ Ṣílómù; òun sì ṣeé kí nwọn kọ́ ilé ìṣọnà nlá kan sí orí òkè tí ó wà ní ìhà àríwá ilẹ̀ Ṣílómù, èyítí ó ti jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn ọmọ Nífáì ní àkokò tí nwọ́n sá kúrò ní ilẹ̀ nã; báyĩ sì ni ó ṣe lo àwọn ọrọ̀ tí ó kójọ nípa gbígba owó-òde lórí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó gbé ọkàn rẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀, ó sì lo ìgbà rẹ̀ nínú ayé ifẹkufẹ pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀; bẹ̃ nã sì ni àwọn àlùfã rẹ ṣe lo ìgbà nwọn pẹ̀lú àwọn panṣágà obìnrin. Ó sì ṣe tí ó sì gbin ọgbà àjàrà yíká ilẹ̀ nã; ó sì kọ́ àwọn ibi ìfúntí, ó sì ṣe ọtí wáìnì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀; ó sì di ọ̀mùtí, àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí gbógun ti àwọn ènìyàn rẹ̀, ní díẹ̀díẹ̀, nwọ́n sì npa nwọ́n nínú oko nwọn, àti nígbàtí nwọ́n bá nṣọ́ agbo-ẹran nwọn. Ọba Nóà rán àwọn olùṣọ́ yí ilẹ̀ nã kãkiri láti lé nwọn sẹ́hìn; ṣùgbọ́n nwọn kò pọ̀ tó, àwọn ará Lámánì sì kọlũ nwọ́n, nwọ́n sì pa nwọ́n, nwọ́n sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbo-ẹran nwọn jáde kúrò ní ilẹ̀ nã; báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀ sí pa nwọ́n run, tí nwọ́n sì nfi ikorira nwọn hàn sí nwọn. Ó sì ṣe tí ọba Nóà rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí nwọn, nwọ́n sì lé nwọn padà, tàbí kí a wípé nwọ́n lé nwọn padà fún ìgbà díẹ̀; nítorínã, nwọ́n padà, nwọ́n yọ̀ nínú ìkógun nwọn. Àti nísisìyí, nítorí ìṣẹ́gun nlá yĩ, nwọ́n gbéraga nínú ìgbéraga ọkàn nwọn; nwọ́n lérí nínú agbára ara nwọn, tí nwọn nwí pé àwọn ãdọ́ta nwọ́n lè dojúkọ àwọn ẹgbẽgbẹ̀rún àwọn ará Lámánì; báyĩ ni nwọ́n sì ṣe lérí, tí nwọ́n sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ àwọn arákùnrin nwọn, èyí sì jẹ́ nítorí ìwà búburú ọba àti àwọn àlùfã nwọn. Ó sì ṣe, tí ọkùnrin kan wà lãrín nwọn tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Ábínádì; ó sì jáde lọ lãrín nwọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ tẹ́lẹ̀, ó wípé: Kíyèsĩ, báyĩ ni Olúwa wí, báyĩ ni ó sì p aláṣẹ fún mi, wípé, Jáde lọ, kí o sì wí fún àwọn ènìyàn yĩ, báyĩ ni Olúwa wí—Ègbé ni fún àwọn ènìyàn yìi, nítorítí mo ti rí ìríra àti ẹ̀gbin nwọn, àti ìwà búburú nwọn, àti ìwà àgbèrè nwọn; àti pé bí nwọn kò bá ronúpìwàdà, èmi yíò bẹ̀ nwọ́n wò nínú ìbínú mi. Àti pé bí nwọn kò bá ronúpìwàdà kí nwọ́n sì padà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn, kíyèsĩ, èmi yíò fi nwọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá nwọn; bẹ̃ni, a ó sì mú nwọn bọ́ sí oko-ẹrú; a ó sì jẹ nwọ́n níyà nípa ọwọ́ àwọn ọ̀tá nwọn. Yíò sì ṣe, tí nwọn yíò mọ̀ wípé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run nwọn, àti pé Ọlọ́run owú ni mí, tí ó nbẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi wò. Yíò sì ṣe wípé bí àwọn ènìyàn yí kò bá ronúpìwàdà, kí nwọ́n yípadà sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn, a ó mu nwọn bọ́ sí oko-ẹrú; kò sì sí ẹni tí yíò gbà nwọ́n là, àfi Olúwa, tí íṣe Ọlọ́run Olódùmarè. Bẹ̃ni, yíò sì ṣe, wípé nígbàtí nwọn bá kígbe pè mí, èmi yíò lọ́ra láti gbọ́ igbe nwọn; bẹ̃ni, èmi yíò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá nwọn kọlũ nwọ́n. Bí nwọn kò bá sì ronúpìwàdà nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú, kí nwọ́n sì kígbe lóhùn rara sí Olúwa Ọlọ́run nwọn, èmi kò ní gbọ́ àdúrà nwọn, bẹ̃ni èmi kò ní gbà nwọ́n lọ́wọ́ ìpọ́njú nwọn; bẹ̃ sì ni Olúwa wí, bẹ̃ sì ni Òun ti pa láṣẹ fún mi. Nísisìyí, ó sì ṣe pé nígbàtí Ábínádì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún nwọn tán, nwọ́n ṣe ìbínú rẹ, nwọ́n sì wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí rẹ; ṣùgbọ́n Olúwa gbã lọ́wọ́ nwọn. Nísisìyí, nígbàtí ọba Nóà ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Ábínádì sọ fún àwọn ènìyàn nã, òun nã ṣe ìbínú; ó sì wípé: Tani Ábínádì, tí èmi àti àwọn ènìyàn mi yíò gba ìdájọ́ rẹ̀, tàbí tani Olúwa, tí yíò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú yí bá àwọn ènìyàn mi? Mo pàṣẹ fún un yín kí ẹ mú Ábínádì wá sí ìhín, kí èmi lè pã, nítorítí ó ti sọ àwọn nkan wọ̀nyí kí ó lè rú àwọn ènìyàn mi sókè kí nwọ́n lè ṣe ìbínú sí ara nwọn, kí nwọ́n sì dá ìjà sílẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn mi; nítorínã èmi yíò pã. Ní báyĩ ojú inú àwọn ènìyàn nã fọ; nítorínã nwọ́n sé àyà nwọn le sí ọ̀rọ̀ Ábínádì, nwọ́n sì nwá láti múu láti ìgbà nã lọ. Ọba Nóà sì sé àyà rẹ̀ le sí ọ̀rọ̀ Olúwa, òun kò sì ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ohun búburú tí ó nṣe. 12 A ju Ábínádì sínú tũbú fún sísọtẹ́lẹ̀ ti ìparun àwọn ènìyàn àti ti ikú ọba Nóà—Àwọn àlùfã èké ntún ọ̀rọ̀ wí jáde láti inú àwọn ìwé-mímọ́, nwọ́n sì nṣe àṣehàn pípa òfin Mósè mọ́—Ábínádì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ nwọn ní òfin mẹ́wã nã. Ní ìwọ̀n ọdún 148 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe lẹ́hìn ìwọ̀n ọdún méjì, tí Ábínádì jáde wá sí ãrín nwọn ní ìparadà, tí nwọn kò mọ̣́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ tẹ́lẹ̀ lãrín nwọn, ó wípé: Báyĩ ni Olúwa pã láṣẹ fún mi, tí ó wípé Ábínádì, lọ kí o sì sọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn mi wọ̀nyí, nítorítí nwọn ti sé àyà nwọn le sí ọ̀rọ̀ mi; nwọ́n kò sì tĩ ronúpìwàdà kúrò nínú ìwà búburú nwọn; nítorínã èmi yíò bẹ̀ nwọ́n wò nínú ìbínú mi, bẹ̃ni, nínú ìbínú tí ó gbóná ni èmi yíò bẹ̀ nwọ́n wò nínú ìwà àìṣedẽdé àti ìríra nwọn. Bẹ̃ni, ègbé ni fún ìran yĩ! Olúwa sì wí fún mi pé: Na ọwọ́ rẹ jáde, kí ó sì sọtẹ́lẹ̀, wípé: Báyĩ ni Olúwa wí, yíò sì ṣe tí ìran yĩ, nítorí ìwà àìṣedẽdé nwọn, a ó mú nwọn bọ́ sí oko-ẹrú, a ó sì gbá nwọn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́; bẹ̃ni, a ó sì lé nwọn nípasẹ̀ àwọn ọmọ ènìyàn, a ó sì pa nwọ́n; àwọn ẹyẹ igún ojú ọ̀run, àti àwọn ajá, bẹ̃ni, àti àwọn ẹranko búburú, yíò jẹ ẹran ara nwọn. Yíò sì ṣe tí a o ka ìgbésí ayé ọba Nóà sí aṣọ inú iná ìléru;nítorítí òun yíò mọ̀ pé èmi ni Olúwa. Yíò sì ṣe tí èmi yíò bá àwọn ènìyàn mi wọ̀nyí jà pẹ̀lú ìpọ́njú kíkorò, bẹ̃ni, pẹ̀lú ìyàn, àti pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn; èmi yíò sì mú kí nwọ́n payinkeke ní gbogbo ọjọ́. Bẹ̃ni, èmi yíò mú kí nwọ́n gbé ẹrù àjàgà lé nwọn lẹ́hìn; a ó sì tì nwọ́n síwájú bĩ odi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Yíò sì ṣe tí èmi yíò wọ̀ yìnyín sí ãrín nwọn, yíò sì pa nwọ́n; èmi yíò sì bá nwọn jà pẹ̀lú ìjì láti ilẹ̀ ìlà oòrùn; àwọn kòkòrò yíò sì yọ ilẹ̀ nwọn lẹ́nu pẹ̀lú, nwọ́n ó sì jẹ ọkà nwọn run. A ó sì bá nwọn jà pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn nlá—gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí ni èmi yíò sì ṣe nítorí ìwà àìṣedẽdé àti ìwà ìríra nwọn. Yíò sì ṣe, pé bí nwọn kò bá ronúpìwàdà, èmi yíò pa nwọ́n run pátápátá kúrò lórí ilẹ̀ ayé; síbẹ̀ nwọn yíò fi àkọsílẹ̀ hàn, èmi yíò sì pa nwọ́n mọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè míràn tí yíò ní ilẹ̀ nã ní ìní; bẹ̃ni, èyí nã ni èmi yíò ṣe kí èmi lè fi ìwà ìríra àwọn ènìyàn wọ̀nyí hàn fún àwọn orílẹ̀-èdè míràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun sì ni Ábínádì sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn yĩ. Ó sì ṣe tí nwọ́n ṣe inúnibíni sí i; nwọ́n sì mú u, nwọ́n gbé e ní dídè lọ sí iwájú ọba, nwọ́n sì wí fún ọba pé: Kíyèsĩ, àti mú ọkùnrin kan wá sí iwájú rẹ èyítí ó ti sọtẹ́lẹ̀ ohun búburú sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ó sì wípé Ọlọ́run yíò pa nwọ́n run. Ó sì tún ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ búburú nípa ìgbésí ayé rẹ, ó sì sọ wípé ayé rẹ yíò dà gẹ́gẹ́bí aṣọ nínú iná ilẽru. Àti pẹ̀lú, ó sọ wípé ìwọ yíò dàbí igi gbígbẹ́ nínú oko, èyítí àwọn ẹranko nrékọjá tí nwọ́n sì ntẹ̀ mọ́lẹ̀. Àti pẹ̀lú, ó sọ wípé ìwọ yíò dàbí ìtànná igi ẹ̀gún, èyítí ó jẹ́ wípé tí ó bá dàgbà tán, tí afẹ́fẹ́ sì fẹ́, yíò di gbígba kiri lórí ilẹ̀. Òun sì nsọ ọ́ bí ẹni pé Olúwa ni ó sọ ọ́ òun sì sọ wípé gbogbo nkan yĩ yíò ṣẹ lé ọ lórí àfi ti ìwọ bá ronúpìwàdà, àti pé èyí rí bẹ̃ nítorí àìṣedẽdé rẹ. Àti nísisìyí, A! ọba, irú ìwà búburú wo ni ìwọ ti hù, tàbí irú ẹ̀ṣẹ̀ ribiribi wo ni àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣẹ̀, tí àwa yíò gba ìdálẹ́bi láti ọwọ́ Ọlọ́run tàbí tí àwa yíò gba ìdájọ́ láti ọwọ́ okùnrin yĩ? Àti nísisìyí A! ọba, kíyèsĩ àwa jẹ́ aláìlẹ́bi, àti ìwọ, A! ọba, kò dẹ́ṣẹ̀; nítorínã, ọkùnrin yĩ ti purọ́ nípa rẹ, ó sì ti sọtẹ́lẹ̀ ní asán. Sì kíyèsĩ, àwa lágbára, àwa kò lè bọ́ sí oko-ẹrú, tàbí kí ọ̀tá wa kó wa ní ìgbèkùn; bẹ̃ni, ìwọ sì ti ṣe rere ní ilẹ̀ nã, ìwọ yíò sì tún ṣe rere síi. Kíyèsĩ, ọkùnrin nã nì èyí, àwa fà á lé ọ lọ́wọ́; ìwọ sì lè ṣe sí i gẹ́gẹ́bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ. Ó sì ṣe tí ọba Nóà mú kí a gbé Ábínádì jù sínú tũbú; ó sì pàṣẹ kí àwọn àlùfã pé jọ kí ó lè ní àjọ ìgbìmọ̀ pẹ̀lú nwọn nípa ohun tí òun yíò fií ṣe. Ó sì ṣe tí nwọ́n sọ fún ọba, wípé: Mú u wá sí ìhín, kí àwa lè ṣe ìwãdí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀; ọba sì pa á láṣẹ pé kí nwọ́n mú u wá sí iwájú nwọn. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìwãdí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ, pé kí nwọ́n lè mú u ṣì sọ, pé nípa èyí nwọn yíò ní èrè-ìdí láti fi ẹ̀sùn kàn án; ṣùgbọ́n ó dá nwọn lóhùn pẹ̀lú ìgboyà, ó sì dojúkọ nwọn lórígbogbo ìbẽrè nwọn, bẹ̃ni, sì ìyalẹ́nu nwọn; nítorítí ó dojúkọ nwọ́n nínú gbogbo ìbẽrè nwọn, ó sì da gbogbo ọ̀rọ̀ nwọn rú mọ́ nwọn lọ́kàn. Ó sí ṣe tí ọ̀kan nínú nwọn wí fún un pé: Kíni ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ, àti ti àwọn bàbá wa kọ́, wípé: Báwo ni ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìhìn-rere ti dára tó lórí àwọn òkè; tí ó nkede àlãfíà; tí ó mú ìhìn-rere ohun rere wá; tí ó nkede ìgbàlà; tí ó wí fún Síónì, Ọlọ́run rẹ̀ njọba; Àwọn alore yíò gbé ohùn sókè; nwọn ó jùmọ̀ fi ohùn kọrin; nítorítí nwọn yíò rí i ní ojúkojú, nígbàtí Olúwa yíò mú Síónì padà bọ̀ wá. Bú sí ayọ̀; ẹ jùmọ̀ kọrin, ẹ̀yin ibi ahoro Jerúsálẹ́mù; nítorítí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó sì ti ra Jerúsálẹ́mù padà; Olúwa ti fi apá rẹ̀ mímọ́ hàn ní ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ìkangun ayé ni yíò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run wa? Àti nísisìyí ni Ábínádì sọ fún nwọn wípé: Ẹ̀yin ha íṣe àlùfã bí, tí ẹ̀yin sì nṣe bí ẹni pé ẹ̀ nkọ́ àwọn ènìyàn yí, àti pé ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ yé yín, síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀yin fẹ́ láti wádĩ lọ́wọ́ mi ohun tí àwọn nkan wọ̀nyí túmọ̀ sí? Èmi wí fún nyín, ègbé ni fún nyín nítorítí ẹ̀yin ti yí ọ̀nà Olúwa po! Nítorípé bí àwọn ohun wọ̀nyí bá yé nyín, ẹ̀yin kò kọ nwọn; nítorínã, ẹ̀yin ti yí ọ̀nà Olúwa po. Ẹ̀yin kò tĩ fi iyè nyín sí òye; nítorínã ẹ̀yin kò tĩ gbọ́n. Nítorínã, kíni ẹ̀yin nkọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Nwọ́n sì wí pé: Àwa nkọ́ òfin Mósè. Òun sì tún wí fún nwọn pé: Bí ẹ̀yin bá nkọ́ òfin Mósè kíni èrè-ìdí rẹ tí ẹ̀yin kò pã mọ́? Kíni èrè-ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin ṣe kó ọkàn nyín lé ọ̀rọ̀? Kíni èrè-ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin ṣe nhùwà àgbèrè tí ẹ̀yin sì nlo agbára yín dànù pẹ̀lú àwọn panṣágà obìnrin, bẹ̃ní, tí ẹ̀yin sì njẹ́ kí àwọn ènìyàn yí dá ẹ̀ṣẹ̀, tí Olúwa fi ní ìdí fún pé kí ó rán mí láti sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn yí, bẹ̃ni, àní ohun búburú sí àwọn ènìyàn yí? Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé òtítọ́ ni èmi nsọ? Bẹ̃ni, ẹ̀yin mọ̀ pé òtítọ́ ni èmi nsọ; ó sì tọ pé kí ẹ wárìrì níwájú Ọlọ́run. Yíò sì ṣe tí a ó jẹ yín níyà fún àwọn àìṣedẽdé nyín, nítorípé ẹ̀yin ti wí pé ẹ̀yin nkọ́ òfin Mósè. Kí ni ẹ̀yin sì mọ̀ nípa òfin Mósè? Njẹ́ ìgbàlà lè wà nípasẹ̀ òfin Mósè? Kíni ẹ̀yin wí? Nwọ́n sì dáhùn, nwọ́n wípé ìgbàlà wá nípasẹ̀ òfin Mósè. Ṣùgbọ́n nísisìyí Ábínádì wí fún nwọn pé: Èmi mọ̀ pé tí ẹ̀yin bá pa awọn òfin Ọlọ́run mọ́, a ó gbà nyín là; bẹ̃ni, tí ẹ̀yin bá pa awọn òfin ti Olúwa gbé lé Mósè lọ́wọ́ ní orí òkè Sínáì mọ, tí ó wípé: Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó ti mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Égíptì, kúrò nínú oko-ẹrú jáde wá. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní Ọlọ́run míràn pẹ̀lú mi. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ya ère-kére fún ara rẹ̀, tàbí àwòrán ohun kan tí mbẹ lókè ọ̀run, tàbí ohun kan tí mbẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Nísisìyí, Ábínádì wí fún nwọn pé, njẹ́ ẹ̀yin ti ṣe gbogboèyí? Èmi wí fún yín, Rárá, ẹ̀yin kò ì tĩ ṣe é. Njẹ́ ẹ̀yin sì ti kọ́ àwọn ènìyàn yí pé kí nwọ́n ṣe gbogbo nkan wọ̀nyí? Èmi wí fún nyin, Rárá, ẹ̀yin kò ì tĩ ṣe é. 13 A dãbò bò Ábínádì pẹ̀lú agbára Ọlọ́run—Ó nkọ́ni ní Òfin Mẹ́wã—Ìgbàlà kò wá nípa òfin Mósè nìkan—Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yíò ṣe ètùtù kan yíò sì ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà. Ní ìwọ̀n ọdún 148 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, nígbàtí ọba ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó sì wí fún àwọn àlùfã rẹ̀ pé: Ẹ mú arákùnrin yĩ kúrò, kí ẹ sì pã; nítorípé kíni àwa ní íṣe pẹ̀lú rẹ̀ nítorípé aṣiwèrè ni íṣe. Nwọ́n sì tẹ̀ síwájú, nwọ́n sì gbìyànjú láti gbé ọwọ́ nwọn lé e; ṣùgbọ́n ó dojúkọ nwọn, ó wí fún nwọn pé: Ẹ máṣe fọwọ́kàn mí, nítorítí Ọlọ́run yíò lù yín tí ẹ bá fọwọ́ bà mí, nítorítí èmi kò ì tĩ jíṣẹ́ ti Olúwa rán mi; bákannã ni èmi kò ì tĩ sọ fún un yín èyítí ẹ̀yin bí mí; nítorínã Ọlọ́run kò ní gbà pé kí ẹ pa mí run ní àkokò yĩ. Ṣùgbọ́n èmi gbọ́dọ̀ mu àwọn òfin èyítí Ọlọ́run pã láṣẹ fún mi ṣẹ; àti nítorípé èmi ti sọ òtítọ́ fún un yín, ẹ̀yin nṣe ìbínú mi. Àti pẹ̀lú, nítorípé èmi sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ẹ̀yin ti pè mí ní aṣiwèrè. Nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ábínádì ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ọba Nóà kò fi ọwọ́ kàn án, nítorítí Ẹ̀mi Olúwa wà lórí rẹ̀; ojú rẹ̀ sì ndán fún ìtànmọ́lẹ̀ tí ó pọ̀ púpọ̀, àní gẹ́gẹ́bí ti Mósè ṣe rí nígbàtí ó wà ní orí-òkè Sínáì, nígbàtí ó nbá Olúwa sọ̀rọ̀. Ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú agbára àti àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; ó si tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó wípé: Ẹ̀yin ríi pé ẹ kò ní agbára láti pa mí, nítorínã èmi parí ọ̀rọ̀ mi. Bẹ̃ni, èmi sì wòye pé ó mú ọkàn an yín gbọgbẹ́, nítorítí èmi sọ òtítọ́ fún un yín nípa àìṣedẽdé e yín. Bẹ̃ni, àwọn ọ̀rọ̀ mi sì mú u yín kún fún ìyanu àti ìtagìrì, àti pẹ̀lú ìbínú. Ṣùgbọ́n èmi parí ọ̀rọ̀ mi; bẹ̃ sì ni kò já mọ́ ohun kan ibití èmi lè lọ, bí èmi bá ti di ẹni-ìgbàlà. Ṣùgbọ́n ohun yĩ ni èmi wí fún yín, ohun tí ẹ̀yin yíò fi mí ṣe, lẹ́hìn èyí, yíò dàbí irú ohun àti ẹ̀ya àwọn ohun tí mbọ̀ wá. Àti nísisìyí mo ka èyítí ó kù nínú àwọn òfin Ọlọ́run síi yín, nítorítí mo wòye pé a kò kọ nwọn sí ọkàn nyín; èmi wòye pé ẹ̀yin ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àìṣedẽdé, ẹ̀yin sì ti fi kọ́ àwọn ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayé nyín. Àti nísisìyí, ẹ̀yin rántí pé mo wí fún nyín wípé: Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ya ère-kére fún ara rẹ, tàbí àwòrán ohun kan tí mbẹ lókè ọ̀run, tàbí ohun kan tí mbẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí èyítí mbẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Àti pẹ̀lú: Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ orí ara rẹ bá fún nwọn, tàbí kí ìwọ sìn nwọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run owú, tí mbẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá wò lára àwọn ọmọ, títí dé ìran kẹ́ta àti ìran kẹ́rin àwọn tí ó korira mi; Tí èmi sì nfi ãnú hàn sí ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àwọn tí nwọnfẹ́ràn mi, tí nwọ́n sì npa awọn òfin mi mọ́. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ lásán; nítorítí Olúwa kí yíò ka àwọn tí ó pe orúkọ rẹ̀ lásán sí aláìlẹ́ṣẹ̀. Rántí ọjọ́ ìsinmi, láti yà á sí mímọ́. Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yíò fi ṣe iṣẹ́, tí ìwọ yíò sì ṣe iṣẹ́ rẹ gbogbo; Ṣùgbọ́n ọjọ́ kéje, ti íṣe ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́, ìwọ, tàbí ọmọ rẹ okùnrin, tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin, tàbí ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin, tàbí ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, tàbí màlũ rẹ, tàbí àlejò rẹ ti mbẹ nínú ibodè rẹ̀; Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run òun ayé, àti òkun, àti gbogbo ohun tí mbẹ nínú rẹ̀; nítorí-èyi ni Olúwa ṣe bùsí ọjọ́ ìsinmi, tí ó sì yã sí mímọ́. Bọ̀wọ̀ fún bàbá òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pànìyàn. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹ̀rí èké sí ẹnìkéjì rẹ. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, tàbí sí ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin, tàbí sí ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, tàbí sí akọ-màlũ rẹ, tàbí sí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tàbí sí ohunkóhun tĩ ṣe ti ẹnìkẹjì rẹ. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ábínádì ti parí sísọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó wí fún nwọn pé: Njẹ́ ẹ̀yin ti kọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé kí nwọ́n ṣe ohun wọ̀nyí láti lè pa àwọn òfin wọ̀nyí mọ́? Mo wí fún nyín, Rárá; nítorítí tí ẹ̀yin bá ti ṣe eleyĩ, Olúwa kì bá ti mú kí èmi jáde wá ati lati sọ asọtẹ́lẹ̀ búburú nípa àwọn ènìyàn yí. Àti nísisìyí ẹ̀yin ti wípé ìgbàlà wá nípa òfin Mósè. Mo wí fún nyín pé ó tọ́ fún nyín pé kí ẹ̀yin kí ó pa òfin Mósè mọ́ síbẹ̀síbẹ̀; ṣùgbọ́n mo wí fún nyín, pé àkokò nã yíò dé tí kò ní tọ́ mọ́ láti pa òfin Mósè mọ́. Àti pãpã, mo wí fún nyín, pé ìgbàlà kò wá nípa òfin nìkan; àti pé tí kò bá ṣe nítorí ètùtù nã, èyítí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yíò ṣe fún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedẽdé àwọn ènìyàn rẹ̀, pé nwọ́n níláti parun dandan, l’áìṣírò òfin Mósè. Àti nísisìyí mo wí fún nyín pé ó tọ́ pé kí a fi òfin kan fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì, bẹ̃ni, àní òfin tí ó le jọjọ; nítorítí nwọ́n jẹ́ ènìyàn ọlọ́rùn líle, tí nwọ́n yára ṣe àìṣedẽdé, tí nwọ́n sì lọ́ra láti rántí Olúwa Ọlọ́run nwọn; Nítorínã òfin kan nbẹ tí a fi fún nwọn, bẹ̃ni, òfin nípa ṣíṣe iṣẹ́ àti ìlànà, òfin tí nwọ́n níláti pamọ́ fínni-fínni láti ọjọ́ kan dé ọjọ́ òmíràn, kí nwọ́n lè wà ní ìrántí Ọlọ́run àti iṣẹ́-ìsìn nwọn sĩ. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, mo wí fún nyín, àwọn nkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀yà àwọn ohun tí mbọ̀ wá. Àti nísisìyí, njẹ́ nwọ́n ní òye òfin nã bí? Mo wí fún nyín, Rárá, gbogbo nwọn kọ́ ní ó ní òye òfin nã; èyí rí bẹ̃ nítorí líle àyà nwọn; nítorítí nwọn kò ní òye wípé kò sí ẹnìkan tí a lè gbalà bíkòṣe nípasẹ̀ ìràpadà Ọlọ́run. Nítorí kíyèsĩ, njẹ́ Mósè kò sọtẹ́lẹ̀ sí nwọn nípa bíbọ̀ Messia,àti pé Ọlọ́run yíò ra àwọn ènìyàn rẹ padà bí? Bẹ̃ni, àní gbogbo àwọn wòlĩ tí nwọ́n ti sọtẹ́lẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé—njẹ́ nwọn kò ha ti sọ̀rọ̀ lọ, sọ̀rọ̀ bọ nípa àwọn ohun wọ̀nyí bí? Njẹ́ nwọn kò t i wípé Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yíò sọ̀kalẹ̀ lãrín ọmọ-ènìyàn, yíò sì gbé àwòrán ènìyàn wọ̀, yíò sì lọ lórí ilẹ̀ ayé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbára? Bẹ̃ni, njẹ́ nwọn kò sì ti wí pẹ̀lú pé yíò mú àjĩnde òkú wá ṣẹ, àti pé kí òun tìkararẹ̀ lè jẹ́ ẹni-ìnilára àti ẹni ìfiyàjẹ? 14 Isaiah sọ̀rọ̀ bĩ Messia—A sọ síwájú nípa ìrẹnisílẹ̀ àti ìjìyà Messia nã—Ó fi ẹ̀mí rẹ rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ó sì nṣe onílàjà fún àwọn olùrékọja—Fi Isaiah 53 wee. Ní ìwọ̀n ọdún 148 kí a tó bí Olúwa wa. Bẹ̃ni, njẹ́ Isaiah kò ha wípé: Tani ó ti gba ìhìn wa gbọ́, àti pé tani ẹnití a fi apá Olúwa hàn sí? Nítorítí yíò dàgbà níwájú rẹ gẹ́gẹ́bí ọ̀jẹ́lẹ́ ewéko, àti gẹ́gẹ́bí gbòngbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ; ìrísí rẹ̀ kò dára, bẹ̃ni kò ní ẹwà; nígbàtí àwa yíò bá sì ríi, kò sí ẹwà tí àwa kò bá fi fẹ́ ẹ. A kẹ́gàn rẹ, a sì kọ̣́ sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn; ẹni ọ̀pọ̀ ìrora-ọkàn, tí ó sì mọ́ ìbànújẹ́; àwa sì fi ojú wa pamọ́ kúrò lára rẹ̀; a kẹ́gàn rẹ̀, àwa kò sì kà á sí. Lọ́ótọ́, ó ti faradà ìbànújẹ́ wa, ó sì ti gbé ìrora-ọkàn wa lọ; síbẹ̀ àwa kà á sí ẹnití a nà, ẹnití Ọlọ́run fìyàjẹ, tí a sì pọ́n lójú. Ṣùgbọ́n a ṣáa lọ́gbẹ́ nítorí ìrékọjá wa, a pã lára nítorí àìṣedẽdé wa; ìbáwí àlãfíà wa wà lára rẹ̀, àti nípa ínà a rẹ̀ ni a fi mú wa lára dá. Gbogbo wa, bí àgùtàn, ni a ti ṣáko lọ; olúkúlùkù wa sì tẹ̀lé ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti mú àìṣedẽdé wa gbogbo pàdé lára rẹ̀. A jẹ ẹ́ ní ìyà, a sì pọ́n ọn lójú, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀; a múu wá bí ọ̀dọ́-àgùtàn fún pípa, àti bí àgùtàn tí ó yadi níwájú àwọn olùrẹ́rùn rẹ̀, bẹ̃ni, kò ya ẹnu rẹ̀. A múu jáde kúrò nínú tũbú, àti kúrò nínú ìdájọ́; tani yíò sì sọ nípa ìran rẹ̀? Nítorítí a ti kée kúrò ní ilẹ̀ alãyè; nítorí ìrékọjá àwọn ènìyàn mi ní a ṣe lũ. Ó sì ṣe ibojì rẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú, pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ rẹ ní ìgbà ikú rẹ̀; nítorípé ko hu ìwà ibi, bẹ̃ni kò sí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀. Síbẹ̀ ó wu Olúwa láti pã lára; ó ti fi sínú ìbànújẹ́; nígbàtí ìwọ o fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, òun yíò rí irú-ọmọ rẹ̀, yíò mú ọjọ́ rẹ̀ gùn, ìfẹ́ Olúwa yíò lọ dẽdé ní ọwọ́ rẹ̀. Òun yíò rí lãlã ẹ̀mí rẹ̀, yíò sì tẹ́ẹ lọ́run; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yíò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre; nítorítí òun yíò ru àìṣedẽdé nwọn. Nítorínã ni èmi yíò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni-nlá, òun yíò sì bá àwọn alágbára pín ìkógun; nítorítí òun ti tú ẹ̀mí rẹ jáde títí dé ikú, a sì kà á mọ́ àwọn olùrékọjá; òun sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe alágbàwí fún àwọn olùrékọjá. 15 Bí Krístì ṣe jẹ́ Bàbá àti Ọmọ—Òun yíò ṣe alágbàwí, yíò sì gbaìrékọjá àwọn ènìyàn rẹ̀—Àwọn àti gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ jẹ́ irú-ọmọ rẹ̀—Ó mú Àjĩnde ṣẹ—Àwọn ọmọdé ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ní ìwọ̀n ọdún 148 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, Ábínádì wí fún nwọn pé: Èmi fẹ́ kí ó yé nyín pé Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yíò sọ̀kalẹ̀ wá sí ãrin àwọn ọmọ ènìyàn, yíò sì ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà. Àti nítorípé ó wà nínú ẹranara, a o pè é ní Ọmọ Ọlọ́run, bí ó sì ti jọ̀wọ́ ẹran ara sí abẹ́ ìfẹ́ Bàbá, tí òun sì jẹ́ Bàbá àti Ọmọ— Bàbá, nítorípé a lóyún rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run; àti Ọmọ, nípasẹ̀ ti ẹran-ara; báyĩ ni ó sì di Bàbá àti Ọmọ— Nwọn sì jẹ́ Ọlọ́run kanṣoṣo, bẹ̃ni, àní Bàbá Ayérayé ti ọ̀run òhun ayé. Báyĩ sì ni ẹran-ara di èyí tí a jọ̀wọ́ rẹ̀ sí abẹ́ Ẹ̀mí, tàbí Ọmọ sí abẹ́ Bàbá, tí nwọ́n jẹ́ Ọlọ́run kanṣoṣo, faradà ìdánwò, kò sì yọ̣́da ara rẹ̀ fún ìdánwò nã, ṣùgbọ́n ó fi ara rẹ̀ sílẹ̀ pé kí a fi ṣe ẹlẹ́yà, kí a nã, kí a sọọ́ síta, kí àwọn ènìyàn rẹ̀ sì kọ̣́. Àti lẹ́hìn gbogbo èyí, lẹ́hìn tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu nlá-nlà lãrín àwọn ọmọ ènìyàn, a o sì sìn jáde, bẹ̃ni, àní gẹ́gẹ́bí Isaiah ṣe sọ, bí àgùtàn tí ó yadi níwájú olùrẹ́rùn rẹ̀, bẹ̃ni kò ya ẹnu rẹ̀. Bẹ̃ni, báyĩ nã ni a o sìn ín lọ, tí a ó kàn án mọ́ àgbélèbú, tí a ó sì pã, tí ẹran-ara yíò di jíjọ̀wọ́ àní títí dé ikú, ìfẹ́ Ọmọ yíò sì di gbígbémì nínú ìfẹ́ Bàbá. Báyĩ sì ni Ọlọ́run já ìdè ikú, nítorítí ó ti gba ìṣẹ́gun lórí ikú; tí ó sì fún Ọmọ ní agbára láti ṣe alágbàwí fún àwọn ọmọ ènìyàn— Tí ó sì gòkè re ọ̀run, tí ó sì ní ọ̀pọ̀ ãnú; ó sì kún fún ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ènìyàn; ó sì dúró lãrín nwọn àti àìṣègbè; tí ó sì ti já ìdè ikú, ó ti gbé àìṣedẽdé nwọn àti ìwàìrékọjá nwọn rù, ó sì ti rà nwọ́n padà, tí ó sì ti tẹ àwọn ìbẽrè àìsègbè lọ́rùn. Àti nísisìyí mo wí fún nyín, tani yíò sọ nípa ìran rẹ̀? Kíyèsĩ mo wí fún nyín, pé nígbàtí a ti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ òun yíò rí irú-ọmọ rẹ̀. Àti nísisìyí kíni ẹ̀yin wí? Tani yíò sì jẹ́ irú-ọmọ rẹ̀? Kíyèsĩ mo wí fún un yín, wípé ẹnìkẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ, bẹ̃ni, gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ tí nwọ́n ti sọtẹ́lẹ̀ nípa bíbọ̀ Olúwa–Mo wí fún nyín wípé gbogbo àwọn tí nwọ́n ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ nwọn, tí nwọ́n sì gbàgbọ́ pé Olúwa yíò ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, tí nwọ́n sì ti nretí ọjọ́ nã fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, mo wí fún nyín, pé àwọn wọ̀nyí ni irú-ọmọ rẹ̀, tàbí àwọn ni ajogún ìjọba Ọlọ́run. Nítorípé àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó ti ru ẹ̀ṣẹ̀ nwọn; àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó kú fún, kí ó lè rà nwọ́n padà kúrò nínú ìwàìrékọjá nwọn. Àti nísisìyí, nwọn kò ha íṣe irú-ọmọ rẹ̀ bí? Bẹ̃ni, njẹ́ àwọn wòlĩ kò ha kĩ ṣe irú-ọmọ rẹ̀ bí, gbogbo nwọn tí nwọ́n ti la ẹnu nwọn láti sọtẹ́lẹ̀, tí kò ṣubú sínú ìwàìrékọjá, àní gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ láti ìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀? Mo wí fún nyín pé, irú-ọmọ rẹ̀ ni nwọ́n íṣe. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ti kéde àlãfíà, tí ó ti mú ìhìnrere ohun rere wá, tí ó ti kédeìgbàlà; tí ó sì wí fún Síónì pé: Ọlọ́run rẹ njọba! A!, báwo ni ẹsẹ̀ nwọn ti dára tó lórí àwọn òkè nã! Àti pẹ̀lú, báwo ni ẹsẹ̀ àwọn tí nwọ́n ṣì nkéde àlãfíà ti dára tó lórí àwọn òkè nã! Àti pẹ̀lú, báwo ni ẹsẹ̀ àwọn tí nwọn yíò kéde àlãfíà ní ọjọ́ tí mbọ̀ ti dára tó lórí àwọn òkè, bẹ̃ni, láti ìgbà yí lọ àti títí láé! Sì kíyèsĩ, mo wí fún nyín, èyí kĩ ṣe gbogbo rẹ̀. Nítorí A!, báwo ni ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìhìn-rere wá ti dára tó lórí àwọn òkè, ẹnití ó jẹ́ olùdásílẹ̀ àlãfíà, bẹ̃ni, àní Olúwa, tí ó ti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà; bẹ̃ni, ẹnití ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìgbàlà; Nítorípé tí kò bá ṣe ti ìràpadà èyítí ó ti ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀, èyítí a ti pèsè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, èmi wí fún un yín, tí kò bá ṣe ti èyí, gbogbo ènìyàn kì bá ti parun. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìdè ikú yíò ja, Ọmọ sì jọba, ó sì ní agbára lórí òkú; nítorínã, ó mú àjĩnde òkú ṣẹ. Àjĩnde kan sì mbọ̀ wá, àní àjĩnde èkíní; bẹ̃ni, àní àjĩnde àwọn tí nwọ́n ti wà, tí nwọ́n wà, tí nwọn yíò sì wà, àní títí dé àjĩnde Krístì—nítorípé bẹ̃ni a ó pẽ. Àti nísisìyí, àjĩnde gbogbo àwọn wòlĩ, àti gbogbo àwọn tí ó gba ọ̀rọ̀ nwọn gbọ́, tàbí gbogbo àwọn tí ó pa awọn òfin Ọlọ́run mọ́, yíò jáde wá ní ìgbà àjĩnde èkíní; nítorínã, àwọn ni àjĩnde èkíní. A gbé nwọn dìde kí nwọ́n lè bá Ọlọ́run gbé, ẹnití ó rà nwọ́n padà; nípa báyĩ nwọ́n ní ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Krístì, ẹnití ó ti já ìdè ikú. Àwọn yĩ sì ni àwọn tí ó ní ìpín nínú àjĩnde èkíní; àwọn yĩ sì ni àwọn tí ó ti kú kí Krístì tó dé, nínú ipò àìmọ̀ nwọn, tí a kò kéde ìgbàlà sí nwọn. Báyĩ sì ni Olúwa mú ìmúpadà sípò àwọn wọ̀nyí ṣẹ; nwọ́n sì ní ìpín nínú àjĩnde èkíní, tàbí ìyè àìnípẹ̀kun, nítorípé Olúwa ti rà nwọ́n padà. Àwọn ọmọdé pẹ̀lú sì ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ẹ bẹ̀rù ẹ sì wárìrì níwájú Ọlọ́run, nítorítí ó yẹ kí ẹ wárìrì; nítorípé Olúwa kò lè ra ẹnití ó ṣọ̀tẹ̀ sí padà, tí nwọ́n sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn; bẹ̃ni, àní gbogbo àwọn tí nwọ́n ti parun nínú ẹ̀ṣẹ̀ ẹ nwọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé, tí nwọ́n ti mọ̣́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, tí nwọ́n ti mọ awọn òfin Ọlọ́run, tí nwọn kò ní pa nwọ́n mọ́; àwọn yí ni nwọn kò ní ìpín nínú àjĩnde èkíní. Nítorínã, kò ha yẹ kí ẹ̀yin kí ó wárìrì bí? Nítorípé ìgbàlà kò sí fún irú àwọn yĩ; nítorípé Olúwa kò ra irú àwọn yĩ padà; bẹ̃ni, Olúwa kò sì lè ra irú àwọn èyí padà; nítorípé Òun kò lè tako ara rẹ̀; nítorípé kò lè tako àìṣègbè nígbàtí ó bá tọ́ ní ṣíṣe. Àti nísisìyí, mo wí fún nyín, pé ìgbà nã yíò dé, tí ìgbàlà olúwa yíò di mímọ̀ fún gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn. Bẹ̃ni, Olúwa, àwọn àlóre rẹ̀ yíò gbé ohun nwọn sókè; nwọn ó jùmọ̀ fi ohùn kọrin; nítorítí nwọn yíò ríi ní ojúkojú, nígbàtí Olúwa yíò mú Síónì padà bọ̀ wá. Bú sí ayọ̀, ẹ jùmọ̀ kọrin, ẹ̀yin ibi ahoro Jerúsálẹ́mù; nítorítíOlúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó ti ra Jerúsálẹ́mù padà. Olúwa ti fi apá rẹ̀ mímọ́ hàn ní ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; gbogbo ikangun ayé ni yíò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run wa. 16 Ọlọ́run nṣe ìràpadà fún ènìyàn kúrò nínú ipò ìpàdánù àti ìṣubú nwọn—Àwọn tí nwọ́n jẹ́ ti ara wà bí èyítí kò ní ìràpadà—Krístì mú wá sí ìmúṣẹ àjĩnde sí ìyè àìnípẹ̀kun tàbí sí ègbé àìnípẹ̀kun. Ní ìwọ̀n ọdún 148 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ábínádì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yĩ ní ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì wípé: Àkokò nã mbọ̀wá tí ènìyàn gbogbo yíò rí ìgbàlà Olúwa; nígbàtí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti àwọn ènìyàn yíò ríi ni ójúkojú, nwọn ó sì jẹ́wọ́ níwájú Ọlọ́run pé ìdájọ́ rẹ̀ jẹ́ èyítí ó tọ́. Nígbànã ni a ó ju àwọn ènìyàn búburú jáde, nwọn yíò sì pohùn réré, wọn yíò sì sọkún, nwọn yíò sì payín kéké; èyí yĩ nítorípé nwọn kò ní fetísílẹ̀ sí ohùn Olúwa; nítorínã Olúwa kò ní rà nwọ́n padà. Nítorítí wọn jẹ́ ti ara, nwọ́n sì jẹ́ ti èṣù, èṣù sì lágbára lórí nwọn; bẹ̃ni, àní ejò ìgbà àtijọ́ nì, èyítí ó tan àwọn obí wa àkọ́kọ́ jẹ; èyítí ó sì jẹ́ ìdí ìṣubú nwọn; èyítí ó mú kí gbogbo ènìyàn jẹ́ ti ara, ti ayé, ti èṣù, tí nwọ́n sì mọ búburú yàtọ̀ sí rere, tí nwọ́n sì fi ara nwọn sílẹ̀ fún èṣù. Báyĩ sì ni ènìyàn gbogbo ṣègbé: sì kíyèsĩ, nwọn kò bá sì ti ṣègbé títí láéláé, bíkòṣepé Ọlọ́run ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà kúrò nínú ipò ìparun àti ìṣubú nwọn. Ṣùgbọ́n ẹ rántí pé ẹnití ó bá tẹ̀síwájú nínú ipò ti ara rẹ̀, tí ó sì lọ ní ipa ẹ̀ṣẹ̀ àti ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wà nínú ipò ìṣubú, èṣù sì ní gbogbo agbára lórí rẹ̀. Nítorínã ó wà bí ẹnití a kò ṣe ìràpadà, nítorítí òun jẹ́ ọ̀tá sí Ọlọ́run; bẹ̃ èṣù sì ni ọ̀tá Ọlọ́run. Àti nísisìyí, tí kò bá jẹ́ pé Krístì wá sínú ayé, tí ó nsọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun èyítí mbọ̀ bí èyítí ó ti dé, kì bá ti sí ìràpadà. Àti pé tí Krístì kò bá ti jínde kúrò nínú òkú, tàbí kí ó ti já ìdè ikú, kí ìsà-òkú má lè ní ìṣẹ́gun, àti kí ikú má lè ní oró, kì bá ti sí àjĩnde. Ṣùgbọ́n àjĩnde wà, nítorínã, ìsà-òkú kò ní ìṣẹ́gun, oró ikú sì jẹ́ gbígbémì nínú Krístì. Òun ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé; bẹ̃ni, ìmọ́lẹ̀ tí ó wà láìnípẹ̀kun, tí a kò lè sọ di òkùnkùn; bẹ̃ni, àti pẹ̀lú iyé tí ó wà láìnípẹ̀kun, tí kò sì ní sí ikú mọ́. Àti pãpã, ara kíkú yí, yíò gbé àìkú wọ̀, bẹ̃ni ìdíbàjẹ́ yĩ yíò gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, a ó sì mú u dúró níwájú itẹ Ọlọ́run kí a lè ṣe ìdájọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ nwọn yálà rere ni nwọ́n tàbí búburú ni nwọ́n í ṣe— Tí nwọ́n bá jẹ́ rere, sí àjĩnde ayé àti ayọ̀ tí kò lópin; tí nwọ́n bá sì jẹ́ búburú, sí àjĩnde sí ègbé áìnípẹ̀kun, tí a ti jọ̀wọ́ nwọn fún èṣù, tí òun sì jọba lé nwọn lórí, èyítí iṣe ègbé— Nítorítí nwọ́n ti lọ sí ipa ìfẹ́-ara nwọn; tí nwọn kò sì ké pé Olúwa nígbàtí a na ọwọ́ ãnú sí nwọn; nítorítí a na ọwọ́ ãnú sínwọn, nwọn kò sì gbà á; a kìlọ̀ fún nwọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, ṣùgbọ́n nwọn kò kọ̀ nwọ́n sílẹ̀; a s ì pã láṣẹ pé kí ní wọ́n ronúpìwàdà, ṣùgbọ́n nwọn kò ronúpìwàdà. Àti nísisìyí, njẹ́ kò ha yẹ kí ẹ̀yin wárìrì kí ẹ sì ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nyín, kí ẹ̀yin kí ó sì rántí pé nínú Krístì àti nípasẹ̀ rẹ̀ nìkan ni ẹ̀yin lè gbàlà bí? Nítorínã, tí ẹ̀yin bá nkọ́ni ní òfin Mósè, kí ẹ̀yin kí ó sì máa kọ́ni wípé ẹ̀yà àwọn ohun tí mbọ̀ wá ni íṣe— Kí ẹ ṣe ìkọ́ni pé ìràpadà wá nípasẹ̀ Krístì Olúwa, ẹnití iṣe Bàbá Ayérayé. Àmín. 17 Álmà gba ọ̀rọ̀ Ábínádì gbọ́, ó sì kọ nwọ́n sílẹ̀—Ábínádì kú ikú iná—Ó sọtẹ́lẹ̀ àrùn àti ikú iná lórí àwọn tí ó pa á. Ní ìwọ̀n ọdún 148 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe, nígbàtí Ábínádì ti parí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí ọba pã láṣẹ kí àwọn àlùfã mú u kí nwọ́n sì pa á. Ṣùgbọ́n ẹnìkan wà lãrín nwọn tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Álmà, òun nã sì jẹ́ àtẹ̀lé ìdílé Nífáì. Ó sì jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin, ó sì gba ọ̀rọ̀ tí Ábínádì ti sọ gbọ́, nítorítí ó mọ̀ nípa àìṣedẽdé èyítí Ábínádì ti jẹ́rĩ sí nwọn; nítorínã ó bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ọba pé kí ó máṣe bínú sí Ábínádì, ṣùgbọ́n kí ó gbà á lãyè kí ó jáde lọ ní àlãfíà. Ṣùgbọ́n ọba bínú sí i, ó sì ní kí nwọ́n ju Álmà sóde kúrò lãrín nwọn, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, kí nwọ́n lè pa á. Ṣùgbọ́n ó sá kúrò níwájú nwọn, ó sì sá pamọ́ kí nwọn má bã rí i. Nígbàtí ó sì ti sá pamọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, ó sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ábínádì ti sọ. Ó sì ṣe, tí ọba pàṣẹ kí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ ka Ábínádì mọ́, kí nwọ́n sì múu; nwọ́n sì dĩ, nwọ́n sì gbée jù sínú túbú. Lẹ̀hìn ọjọ́ mẹ́ta, lẹ́hìn tí ó ti bá àwọn àlùfã a rẹ̀ dámọ̀ràn, ó pàṣẹ kí nwọ́n tún mú u wá síwájú òun. Ó sì wí fún un pé: Ábínádì, àwa ti fi ẹ̀sùn kàn ọ́, ikú sì tọ́ sí ọ. Nítorítí ìwọ ti sọ wípé kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ wá sí ãrín àwọn ọmọ ènìyàn; àti nísisìyí, fún ìdí èyí a ó pa ọ́, àfi tí ìwọ bá sẹ́ gbogbo ọ̀rọ̀ búburú tí ìwọ ti sọ nípa mi àti àwọn ènìyàn mi. Nísisìyí, Ábínádì wí fún un pé: Mo wí fún ọ, èmi kò lè sẹ́ ọ̀rọ̀ tí èmi ti wí fún ọ nípa àwọn ènìyàn yí, nítorípé òtítọ́ ni nwọ́n; kí ìwọ kí ó sì lè ní ìdánilójú nípa nwọn ni èmi ṣe gbà kí èmi kí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀ rẹ. Bẹ̃ni, èmi yíò jìyà àní títí dé ikú, èmi kò sì ní sẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi, nwọn yíò sì dúró gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí sí ọ. Tí ìwọ bá si pa mí, ìwọ yíò ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, èyí yíò sì tún dúró gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí sí ọ ní ọjọ́ ìkẹhìn. Àti nísisìyí, ọba Nóà sì ṣetán láti tú u sílẹ̀, nítorítí ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ̀; nítorítí ó bẹ̀rù pé ìdájọ́ Ọlọ́run yíò de sórí òun. Ṣùgbọ́n àwọn àlùfã gbé ohùn nwọn sókè ta kò ó, nwọ́n bẹ̀rẹ̀ síi fi ẹ̀sùn kàn án, wípé: Ó ti kẹ́gàn ọba. Nítorínã, a rú ọbasókè ní ìbínú síi, òun sì jọ̀wọ́ ọ rẹ̀ sílẹ̀ fún pípa. Ó sì ṣe tí nwọ́n múu, nwọ́n sì dè é, nwọ́n sì jẹ ẹran ara rẹ̀ níyà, pẹ̀lú ẹ̀rú igi, àní títí dé ojú ikú. Àti nísisìyí, nígbàtí ọ̀wọ́ iná nã bẹ̀rẹ̀ sí jó o, ó kígbe sí nwọn lóhùn rara, wípé: Ẹ kíyèsĩ, gẹ́gẹ́bí ẹ̀yin ti ṣe sí mi, bẹ̃ni yíò rí tí àwọn irú-ọmọ nyín yíò ṣe tí ọ̀pọ̀ ènìyàn yíò jẹ ìrora oró ikú nípa iná bí èmi ti njẹ ìrora; èyí sì rí bẹ̃ nítorítí nwọ́n gbàgbọ́ nínú ìgbàlà Olúwa Ọlọ́run nwọn. Yíò sì ṣe, tí a ó fi onírurú àrùn bẹ̀ yín wò nítorí àìṣedẽdé nyín. Bẹ̃ni, a ó kọlũ yín ní gbogbo ọ̀nà, a ó sì fọ́n nyín ká kiri síwá àti sẹ́hìn, àní gẹ́gẹ́bí ọ̀wọ́ ẹran ti ẹranko búburú inú ìgbẹ́ nfọ́n-ká. Àti ní ọjọ́ nì, a ó dọdẹ nyín àwọn ọ̀tá yíò sì mú nyín, nígbànã àní ẹ̀yin yíò jìyà, bí èmi ti jìyà pẹ̀lú, ìrora oró ikú nípa iná. Báyĩ, ni Ọlọ́run san ẹ̀san fún àwọn tí ó pa àwọn ènìyàn rẹ̀ run. A! Ọlọ́run, gba ẹ̀mí mi. Àti nísisìyí, nígbàtí Ábínádì sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó ṣubú lulẹ̀, nítorítí ó ti kú ikú iná; bẹ̃ni, nítorítí a ti pa á nítorípé kò ní sẹ́ àṣẹ Ọlọ́run, tí ó sì ti fi èdìdì di òtítọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ikú rẹ̀. 18 Álmà nwãsù ní ìkọ̀kọ̀—Ó ṣe ìlànà májẹ̀mú ìrìbọmi, ó sì nṣe rìbọmi nínú àwọn omi Mọ́mọ́nì—Ó ṣe ìkójọ ìjọ Krístì, ó sì yan àwọn àlùfã—Nwọ́n npèsè fún ara nwọn, nwọ́n sì nkọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́—Álmà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ sá kúrò níwájú Ọba Nóà, lọ sínú aginjù. Ní ìwọ̀n ọdún 147 sí 145 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ó sì ṣe tí Álmà, ẹnití ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọba Nóà, ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedẽdé rẹ̀, ó sì nlọ ní ìkọ̀kọ̀ lãrín àwọn ènìyàn, ó sì bẹ̀rẹ̀sí nkọ́ nwọn ní ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ábínádì— Bẹ̃ni, nípa èyítí nbọ̀ wá, àti pẹ̀lú nípa àjĩnde òkú, àti ìràpadà àwọn ènìyàn, èyítí a ó múṣẹ nípa agbára àti ìjìyà, àti ikú Krístì, àti àjĩnde òun ìgòkè re ọ̀run rẹ̀. Àti gbogbo ẹnití ó gbọ́ ohùn rẹ̀ ni ó kọ́ ní ẹ̀kọ́. Ó sì kọ́ nwọn ní ìkọ̀kọ̀, pé kí ó má di mímọ̀ sí ọba. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó sì gba ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ gbọ́. Ó sì ṣe, pé gbogbo ẹnití ó gbã gbọ́ ni ó lọ sí ibì kan tí a pè ní Mọ́mọ́nì, èyítí ó ti gba orúkọ rẹ̀ láti ọwọ́ ọba, tí ó wà ní ikangun ilẹ̀ nã, tí àwọn ẹranko búburú sì ngbé ibẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Ní báyĩ, orísun omi tí ó mọ́ kan wà ní Mọ́mọ́nì, Álmà sì kọjá lọ sibẹ̀, igbó ṣũrú kan sì wà ní ẹ̀gbẹ́ omi nã, níbití ó fi ara rẹ̀ pamọ́ sí ní ọ̀sán kúrò lọ́wọ́ ìwákiri ọba. Ó sì ṣe, tí gbogbo ẹnití ó gbà á gbọ́ ni ó lọ sí ibẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì ṣe lẹ́hìn ọjọ́ pípẹ́, àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn kó ara nwọn jọ sí ibi tí à npè ní Mọ́mọ́nì, láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Álmà. Bẹ̃ni, gbogbo nwọn kójọ, àwọn tí nwọ́n gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, láti gbọ́ ọ. Ó sì kọ́ nwọnní ẹ̀kọ́, ó sì wãsù sí nwọn fún ìrònúpìwàdà àti ìràpadà, àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa. Ó sì ṣe, tí ó wí fún nwọn pé: Kíyèsĩ, àwọn wọ̀nyí ni omi Mọ́mọ́nì (nítorípé báyĩ ni à npè nwọ́n) ati nísisìyí, bí ẹ̀yin ti ṣe ní ìfẹ́ láti wá sínú agbo Ọlọ́run, kí a sì pè nyín ní ènìyàn rẹ̀, tí ẹ sì ṣetán láti fi ara dà ìnira ara nyín, kí nwọ́n lè fúyẹ́; Bẹ̃ni, tí ẹ̀yin sì ṣetán láti ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tí nṣọ̀fọ̀; bẹ̃ni, àti láti tu àwọn tí ó fẹ́ ìtùnú nínú, àti láti dúró gẹ́gẹ́bí àwọn ẹlẹ́rĩ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo àti níbi gbogbo tí ẹ̀yin lè wà, àní títí dé ojú ikú, kí a lè rà yín padà nípasẹ̀ Ọlọ́run, kí a sì kà yín mọ́ ara àwọn tí ó ní àjĩnde èkíní, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun— Nísisìyí mo wí fún nyín, tí èyí bá jẹ́ ìfẹ́ ọkàn nyín, kíni ẹ̀yin ní tí ó jẹ́ ìdènà sí kí a rì nyín bọmi ní orúkọ Olúwa, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí níwájú rẹ̀ wípé ẹ̀yin ti bá a dá májẹ̀mú, pé ẹ̀yin yíò máa sìn in, ẹ̀yin yíò sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, kí Òun kí ó lè da Ẹ̀mí rẹ̀ lé nyín lórí lọ́pọ̀lọpọ̀? Àti nísisìyí, nígbàtí àwọn ènìyàn nã ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nwọ́n pàtẹ́wọ́ fún ayọ̀, nwọ́n sì kígbe sókè: Èyí ni ìfẹ́ ọkàn wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe, tí Álmà mú Hẹ́lámì, ẹnití ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́, ó sì lọ dúró nínú omi nã ó sì ké rara, ó wípé: Á!, Olúwa, da Ẹ̀mí rẹ lé orí ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ, kí òun kí ó lè ṣe iṣẹ́ yĩ pẹ̀lú ọkàn mímọ́. Nígbàtí ó sì ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Ẹ̀mí Olúwa sì bà lée, ó wipe: Hẹ́lámì, Mo rì ọ́ bọmi, nítorítí èmi ní àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Olódùmarè, fún ẹ̀rí pé ìwọ ti wọ inú májẹ̀mú láti sìn ín, títí dé ojú ikú ni ti ara; kí Ẹ̀mí Olúwa sì dà lé ọ lórí; kí òun kí ó sì fún ọ ní ìyè àìnípẹ̀kun, nípasẹ̀ ìràpadà ti Krístì, èyítí ó ti pèsè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Nígbatí Álmà sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Álmà àti Hẹ́lámì tẹ ara nwọn rì sínú omi nã; nwọ́n sì dìde sókè, nwọ́n sì jáde kúrò nínú omi pẹ̀lú àjọyọ̀, tí nwọ́n sì kún fún Ẹ̀mí. Àti pẹ̀lú, Álmà mú ẹlòmíràn, ó sì kọjá lọ sínú omi nã lẹ̃kejì, ó sì rĩ bọmi gẹ́gẹ́bí ti ẹni àkọ́kọ́, àfi pé kò ri ara rẹ̀ bọmi mọ́. Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ yí ni ó ṣe ìrìbọmi fun gbogbo ẹni tí ó kọjá lọ sí ibi ti Mọ́mọ́nì; nwọ́n sì pọ̀ tó ọgọ̣́rún méjì àti mẹ́rin ènìyàn; bẹ̃ni, a sì rì nwọn bọmi nínú omi Mọ́mọ́nì, nwọ́n sì kún fún ọ́re ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. A sì pè nwọ́n ní ìjọ Ọlọ́run tàbí ìjọ Krístì, láti ìgbà nã lọ. Ó sì ṣe, tí ẹnìkẹ́ni tí a bá ti ṣe ìrìbọmi fún nípasẹ̀ agbára àti àṣẹ Ọlọ́run ni a fi kún ìjọ rẹ̀. Ó sì ṣe tí Álmà ẹ̀nití ó ní àṣẹ láti ọwọ́ Ọlọ́run, yan àwọn àlùfã; àní àlùfã kan fún ãdọ́tà nwọn, ni ó yàn láti wãsù sí nwọn, àti fún kíkọ́ nwọn nípa àwọn ohun ìjọba Ọlọ́run. Ó sì pàṣẹ fún nwọn pé kí nwọ́n máṣe kọ́ ohunkóhun yàtọ̀ sí àwọn ohun èyítí òun ti kọ́, tí a sì ti sọ lati ẹnu àwọn wòlĩ mímọ́. Bẹ̃ni, òun pẹ̀lú pàṣẹ fún nwọn pé kí nwọ́n máṣe wãsù ohun míràn tí ó yàtọ̀ sí ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínúOlúwa, ẹnití ó ti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà. Ó sì pàṣẹ fún nwọn pé kí asọ̀ máṣe wà lãrín nwọn, ṣùgbọ́n kí nwọ́n wo iwaju pẹ̀lú ojúkanna, nínú ìgbàgbọ́ kan, ìrìbọmi kan, pẹ̀lú ọkàn kan sí ara nwọn, ní ìṣọ̀kan àti ní ìfẹ́ ọ̀kan sí òmíràn. Báyĩ ni ó sì ṣe pàṣẹ fún nwọn láti wãsù. Báyĩ ni nwọ́n sì di ọmọ Ọlọ́run. Ó sì pàṣẹ fún nwọn pé kí nwọ́n rántí ọjọ́ ìsinmi, kí nwọ́n sì yà á sí mímọ́, àti pẹ̀lú lójojúmọ́, kí nwọ́n máa fi ọpẹ́ fún Olúwa Olọ́run nwọn. Ó sì tún pàṣẹ fún nwọn pé kí àwọn àlùfã tí òun ti yàn máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ nwọn fún ohun ìtọ́jú ara nwọn. Ọjọ́ kan sì wà nínú ọ̀sẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ pé kí nwọ́n kó ara nwọn jọ láti kọ́ àwọn ènìyàn nã, àti láti sin Olúwa Ọlọ́run nwọn, àti pẹ̀lú, nígbà-kũgbà tí ó bá ṣeéṣe fún nwọn, kí nwọ́n péjọ pọ̀. Àwọn à l ù f ã nã kò s ì gbọ́dọ̀ gbójúlé àwọn ènìyàn fún ìrànlọ́wọ́ nwọn; ṣùgbọ́n fún iṣẹ́-ìsìn nwọn, nwọn o rí ọ́re-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run gbà, kí nwọn lè di alágbára nínú Ẹ̀mí, pẹ̀lú ìmọ̀ nwọ́n ní ìmọ̀ nínú Ọlọ́run, kí nwọn kí ó lè kọ́ni pẹ̀lú agbára àti àṣẹ láti ọwọ́ Ọlọ́run. Àti pẹ̀lú, Álmà pàṣẹ pé kí àwọn ènìyàn ìjọ nã fifún ni nínú ohun ìní nwọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí èyítí ó ní; bí ó bá ní ọ̀rọ̀ púpọ̀, kí ó fífúnni púpọ̀; ẹnití ó sì ní díẹ̀, díẹ̀ ni kí ó fifúnni; kí a sì fifún ẹnití ó ṣe aláìní. Báyĩ sì ní kí nwọ́n ṣe fifún ni nínú ohun ìní nwọn, pẹ̀lú ìfẹ́ àtinúwá pẹ̀lú inúrere sí Ọlọ́run, àti sí àwọn àlùfã tí nwọ́n ṣe aláìní, bẹ̃ ni, àti sí gbogbo aláìní, ẹnití ó wà ni ìhòhò. Èyí ni ó sì wí fún nwọn, nítorítí Ọlọ́run ti pã láṣẹ fún un; nwọ́n sì nrìn ní ìdúróṣinṣin níwájú Ọlọ́run, nwọ́n sì nfifún olúkúlùkù ara nwọn, àwọn ohun ti ara àti ohun ti ẹ̀mí, gẹ́gẹ́bí àìní àti àìtó nwọn. Àti nísisìyí, ó sì ṣe tí a ṣe gbogbo nkan wọ̀nyí ní Mọ́mọ́nì, bẹ̃ni, ní ẹ̀gbẹ́ odò Mọ́mọ́nì, nínú igbó èyítí ó wà ní itòsí odò Mọ́mọ́nì; bẹ̃ni, ibi Mọ́mọ́nì, odò Mọ́mọ́nì, igbó Mọ́mọ́nì, báwo ni nwọ́n ṣe lẹ́wà tó ní ojú àwọn t í nwọ́n ní ìmọ̀ Olùràpadà nwọn; bẹ̃ni, báwo sì ni nwọ́n ṣe jẹ́ alábùkún-fún tó, nítorí nwọn yíò máa kọrin ìyìn rẹ̀ títí láé. Àwọn nkan wọ̀nyí ni a sì ṣe ní etí ìpínlẹ̀ nã, kí nwọn má bã di mímọ̀ sí ọba. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ó sì ṣe tí ọba ṣe àwàrí ìṣípòpadà kan lãrín àwọn ènìyàn nã, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí nwọ́n lọ ṣọ́ nwọn. Nítorínã, ní ọjọ́ tí nwọ́n npéjọpọ̀ pé kí nwọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, nwọ́n ṣe àwárí nwọn fún ọba. Àti nísisìyí, ọba sọ wípé Álmà nrú àwọn ènìyàn sókè sí ìṣọ̀tẹ̀ sí òun; nítorínã ó rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti pa wọ́n run. Ó sì ṣe tí Álmà àti àwọn ènìyàn Olúwa gbọ́ nípa bíbọ̀ àwọn ọmọ ogun ọba; nítorínã nwọ́n kó àgọ́ nwọn pẹ̀lú ẹbí nwọn, nwọ́n kọjá lọ sínú aginjù. Nwọ́n sì tó ọgọ̣́rún mẹ́rin àti ãdọ́ta ènìyàn. 19 Gídéónì nwá ọ̀nà láti pa ọba Nóà—Àwọn ara Lámánì dótì ilẹ̀ nã—Ọba Nóà kú ikú iná—Límháì ṣe ìjọba sísan owó ìsìn. Ní ìwọ̀n ọdún 145 sí 121 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí àwọn ọmọ ogun ọba padà, lẹ́hìn tí nwọ́n wá àwọn ènìyàn Olúwa lórí asán. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, àwọn ọmọ ogun ọba kéré, nítorítí nwọ́n ti dínkù, ìyapa sì bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín àwọn ènìyàn tí ó kù. Àwọn ìpín tí ó kéré jù sì bẹ̀rẹ̀sí mí ìmí ìkìlọ̀ sí ọba, asọ̀ púpọ̀púpọ̀ sì bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín nwọn. Àti nísisìyí, ọkùnrin kan wà lãrín nwọn tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Gídéónì, ó sì jẹ́ alágbára ènìyàn, àti ọ̀tá sí ọba, nítorínã, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì búra nínú ìbínú rẹ pé òun yíò pa ọba. Ó sì ṣe tí ó bá ọba jà; nígbàtí ọba sì ríi pé ó fẹ́rẹ̀ borí òun, ó sálọ, ó sì sáré lọ sí orí ilé ìṣọ́ gíga èyítí ó wà ní itòsí tẹ́mpìlì. Gídéónì sì sá tẹ̀le e, nígbàtí ó sì fẹ́rẹ̀ dé ibi ilé ìṣọ́ gíga nã láti pa ọba, ọba sì wò yíká kiri sí apá ilẹ̀ Ṣẹ́múlónì, sì kíyèsĩ àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì wà ní etí ilẹ̀ nã. Àti nísisìyí, ọba kígbe sókè nínú àròkàn ọkàn rẹ̀, wípé: Gídéónì, dá mi sí, nítorítí àwọn ará Lámánì ti kọ lù wá nwọn ó sì pa wá run; bẹ̃ni, nwọn ó pa àwọn ènìyàn mi run. Àti nísisìyí, ọba kò ro ti àwọn ènìyàn rẹ tó bí òun ṣe ro ti ẹ̀mí ara tirẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Gídéónì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ọba sí pàṣẹ fún àwọn ènìyàn nã pé kí nwọ́n sá fún àwọn ará Lámánì, òun fúnra rẹ̀ sì sá lọ níwájú nwọn, nwọ́n sì sá lọ sínú aginjù, pẹ̀lú àwọn obìnrin nwọn àti àwọn ọmọ nwọn. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámání sá tẹ̀lé nwọn, tí nwọ́n sì bá nwọn, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n. Nísisìyí, ó sì ṣe tí ọba pàṣẹ fún nwọn pé kí gbogbo àwọn ọkùnrin fi ìyàwó àti àwọn ọmọ nwọn sílẹ̀, kí nwọ́n sì sá fún àwọn ará Lámánì. Nísisìyí, àwọn tí nwọn kò fẹ́ láti fi nwọ́n sílẹ̀ pọ̀ púpọ̀, tí ó tẹ́ nwọn lọ́rùn láti dúró kí nwọ́n sì parun pẹ̀lú nwọn. Àwọn yókù sì fi àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ nwọ́n sílẹ̀, nwọ́n sì sálọ. Ó sì ṣe tí àwọn tí ó dúró pẹ̀lú ìyàwó àti àwọn ọmọ nwọn, mú kí àwọn ọmọbìnrin nwọn tí ó lẹ́wà jáde, kí nwọ́n sì ṣípẹ̀ fún àwọn ará Lámánì pé kí nwọ́n máṣe pa nwọ́n. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì ṣãnú fún nwọn, nítorítí ẹwà àwọn obìnrin nwọn tù nwọ́n lójú. Nítorínã, àwọn ará Lámánì dá ẹ̀mí nwọn sí, nwọ́n sì mú nwọn ní ìgbèkùn, nwọ́n sì gbé nwọn padà lọ sí ilẹ̀ Nífáì, nwọ́n sì gbà fún nwọn kí nwọ́n ní ilẹ̀ nã fún ìdí èyítí nwọn ó jọ̀wọ́ ọba Nóà lé àwọn ará Lámánì lọ́wọ́, tí nwọn yíò sì jọ̀wọ́ ohun ìní nwọn, àní ìdásíméjì ohun gbogbo tí nwọ́n ní, ìdásíméjì wúrà nwọn, àti fàdákà nwọn, àti ohun gbogbo olówó iyebíyetí nwọ́n ní, báyĩ sì ni nwọn yíò san owó-òde fún ọba àwọn ará Lámánì ní ọdọdún. Àti nísisìyí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba wà lãrín àwọn tí a mú ní ìgbèkùn, tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Límháì. Àti nísisìyí, Límháì ní ìfẹ́ kí bàbá òun máṣe ṣègbé; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Límháì kò ṣe àìmọ̀ nípa gbogbo àìṣedẽdé bàbá rẹ̀, nítorítí òun fúnra rẹ jẹ́ ènìyán tí ó tọ́. Ó sì ṣe tí Gídéónì rán àwọn ènìyàn lọ sínú aginjù ní ìkọ̀kọ̀, láti lè wá ọba àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ lọ. Ó sì ṣe, tí nwọ́n bá àwọn ènìyàn nã ní inú aginjù, gbogbo nwọn àfi ọba àti àwọn àlùfã rẹ. Nísisìyí, nwọ́n ti búra nínú ọkàn nwọn pé nwọn yíò padà sí ilẹ̀ Nífáì, àti pé bí a bá pa àwọn ìyàwó nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn, àti àwọn tí ó dúró ti nwọ́n, pé àwọn yíò gbẹ̀san, kí nwọ́n sì parun pẹ̀lú nwọn. Ọba sì pàṣẹ pé kí nwọ́n máṣe padà; nwọ́n sì bínú sí ọba, nwọ́n sì mú kí ó jìyà, àní títí dé ojú ikú nípasẹ̀ iná. Nwọ́n sì gbìyànjú láti mú àwọn àlùfã pẹ̀lú kí nwọ́n sì pa nwọ́n, nwọ́n sì sá lọ mọ́ nwọn lọ́wọ́. Ó sì ṣe, tí nwọ́n gbìyànjú láti padà lọ sí ilẹ̀ Nífáì, nwọ́n sì pàdé àwọn ará Gídéónì. Àwọn ará Gídéónì sì wí fún nwọn nípa gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìyàwó nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn, àti pé àwọn ará Lámánì ti gbà fún nwọn kí nwọ́n ṣe ìní ilẹ̀ nã nípa sísan owó-òde fún àwọn ará Lámánì èyí tí iṣe ìdajì ohun ìní nwọn. Àwọn ènìyàn nã sì sọ fún àwọn ará Gídéónì pé nwọ́n ti pa ọba, tí àwọn àlùfã rẹ̀ sì ti sálọ jìnà sínú aginjù. Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí nwọ́n ti parí ètò nã, tí nwọ́n padà lọ sí ilẹ̀ Nífáì, tayọ̀-tayọ̀, nítorípé a kò pa àwọn ìyàwó àti ọmọ nwọn; nwọ́n sì sọ ohun tí nwọ́n ti ṣe fún ọba fún Gídéónì. Ó sì ṣe tí ọba àwọn ará Lámánì dá májẹ̀mú pẹ̀lú nwọn wípé àwọn ènìyàn òun kò gbọ́dọ̀ pa nwọ́n. Límháì pẹ̀lú, ẹnití íṣe ọmọ ọba, ẹnití a gbé ìjọba lé lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, bá ọba àwọn ará Lámánì dá májẹ̀mú wípé àwọn ènìyàn òun gbọ́dọ̀ san owó-òde fún un; àní ìdásíméjì gbogbo ohun ìní nwọn. Ó sì ṣe tí Límháì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìjọba nã lélẹ̀, àti láti fi àlãfíà lélẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀. Ọba àwọn ará Lámánì sì fi ìṣọ́ yí ilẹ̀ nã kãkiri, kí òun kí ó lè sé àwọn ará Límháì mọ́ inú ilẹ̀ nã, kí nwọn kí ó má lè kọjá sínú aginjù; òun sì nbọ́ àwọn ìṣọ́ rẹ pẹ̀lú owó-òde tí ó gbà láti ọwọ́ àwọn ará Nífáì. Àti nísisìyí ọba Límháì sì ní àlãfíà pẹ́ títí nínú ìjọba rẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì, tí àwọn ará Lámánì kò yọ nwọn lẹ́nu, tí nwọn kò sì lépa láti pa nwọ́n run. 20 Àwọn ọmọbìnrin Lámánì kan di jíjígbé láti ọwọ́ àwọn àlùfã Nóà—Àwọn ará Lámánì gbógun ti Límháì àti àwọn ènìyàn rẹ̀—Ádá àwọn ọmọ ogun Lámánì padà, a sì tù nwọ́n nínú. Ní ìwọ̀n ọdún 145 sí 123 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí, agbègbè kan wà ní Ṣẹ́múlónì tí àwọn ọmọbìnrin Lámánì a máa péjọpọ̀ sí fún orin kíkọ, àti fún ijó, àti láti dá inú ara nwọn dùn. Ó sí ṣe ní ọjọ́ kan tí díẹ̀ nínú nwọn ti péjọpọ̀ fún orin kíkọ́ àti ijó. Àti nísisìyí àwọn àlùfã ọba Nóà, nítorípé ojú tì nwọ́n láti padà sí ìlú ti Nífáì, bẹ̃ni, àti nítorípé nwọ́n sì bẹ̀rù pé àwọn ènìyàn yíò pa nwọ́n, nítorínã nwọn kò padà sọ́dọ̀ àwọn ìyàwó àti ọmọ nwọn. Nítorípé nwọ́n ti dúró sínú aginjù, tí nwọ́n sì ti wá àwọn ọmọbìnrin Lámánì rí, nwọ́n sá pamọ́ nwọ́n sì nṣọ́ nwọn; Nígbàtí àwọn díẹ̀ nínú nwọn sì péjọpọ̀ láti jó, nwọ́n jáde síta kúrò ní ibití nwọ́n sá pamọ́ sí, nwọ́n mú nwọn, nwọ́n sì gbé nwọn lọ sínú aginjù; bẹ̃ni, ogún àti mẹ́rin àwọn ọmọbìnrin Lámánì ni nwọ́n gbé lọ sínú aginjù. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì rí i pé nwọn kò rí àwọn ọmọbìnrin nwọn mọ́, nwọ́n bínú sí àwọn ará Límháì, nítorítí nwọ́n rò wípé àwọn ará Límháì ni. Nítorínã, nwọ́n fi àwọn ọmọ ogun nwọn ránṣẹ́; bẹ̃ni, àní ọba fúnrarẹ̀ lọ níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀; nwọ́n sì kọjá lọ sí ilẹ̀ Nífáì láti lọ kọlũ àwọn ará Límháì. Àti nísisìyí, Límháì ti rí nwọn láti orí ilé ìṣọnà, àní gbogbo ìmúrasílẹ̀ fún ogun tí nwọn nṣe ní ó rí; nítorínã ó pe àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ, nwọ́n sì ba pamọ́ dè nwọn nínú pápá àti nínú igbó. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí àwọn ará Lámánì ti gòkè wá, ni àwọn ènìyàn Límháì bẹ̀rẹ̀sí kọ lù nwọ́n ní ibi tí nwọ́n dúró sí, nwọ́n sì npa nwọ́n. Ó sì ṣe tí ogun nã gbóná púpọ̀púpọ̀, nítorípé nwọ́n jà bĩ awọn kìnìún fún ohun ọdẹ wọn. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn Límháì bẹ̀rẹ̀sí lé àwọn ará Lámánì lọ níwájú nwọn; síbẹ̀síbẹ̀, nwọn kò pọ̀ tó ìdajì àwọn ará Lámánì. Ṣùgbọ́n nwọ́n jà fún ẹ̀mí nwọn, àti fún àwọn ìyàwó nwọn, àti fún àwọn ọmọ nwọn; nítorínã, nwọ́n lo gbogbo agbára nwọn, gẹ́gẹ́bí drágónì ni nwọn sì jà. Ó sì ṣe, tí nwọ́n rí ọba àwọn Lámánì lãrín àwọn tí ó tí kú; síbẹ̀ kò ì tĩ kú, títorítí ó ti fara gbọgbẹ́, tí a sì ti fi sílẹ̀ lẹ́hìn, tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ti sálọ kankan. Nwọ́n sì mú u, nwọ́n sì di ọ́gbẹ́ rẹ̀, nwọ́n sì mú u wá sí iwájú Límháì, nwọ́n sì wípé: kíyèsĩ, èyí yĩ ni ọba àwọn ará Lámánì; ẹnití ó ti gbọgbẹ́ tí ó sì ṣubú sí ãrin àwọn ènìyàn nwọn tí ó kú, tí nwọ́n sì fĩ sílẹ̀; sì kíyèsĩ, àwa mú u wá sí iwájú rẹ; àti nísisìyí, jẹ́ kí àwa kí ó pa á. Ṣùgbọ́n Límháì wí fún nwọn pé: Ẹ̀yin kò ní pa á, ṣùgbọ́n ẹ mú u wá sí ìhín, kí èmi kí ó lè rí i. Nwọ́n sì mú u wá. Límháì sì wí fún un pé: Kíni ìdí rẹ̀ tí ìwọ fi wá bá àwọn ènìyàn mi jagun? Kíyèsĩ àwọn ènìyàn mi kò sẹ́ májẹ̀mú nã tí èmi dá pẹ̀lú yín; nítorínã, kíni ìdí rẹ tí ẹ̀yin fi sẹ́ májẹ̀mú nã tí ẹ̀yin bá àwọn ènìyàn mi dá? Àti nísisìyí ọba nã sì wípé: Èmi sẹ́ májẹ̀mú nã nítorípé àwọn ènìyàn rẹ jí àwọn ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi gbé sálọ; nítorínã, nínú ìbínú mi ni èmi mú kí àwọn ènìyàn mi wá bá àwọn ènìyàn rẹ jà. Àti nísisìyí Límháì kò tĩ gbọ́ ohunkóhun nípa ọ̀rọ̀ yíi; nítorínã ó wípé: Èmi yíò ṣe ìwãdí lãrín àwọn ènìyàn mi, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe èyí yíò parun. Nítorínã ó pàṣẹ pé kí a ṣe ìwãdí lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀. Nísisìyí, nígbàtí Gídéónì ti gbọ́ ohun wọ̀nyí, nítorítí òun jẹ́ balógun ọba, ó tọ ọba lọ, ó sì wí fún un pé: Èmi bẹ̀ ọ́, dáwọ́ dúró, kí o máṣe ṣe ìwãdí lãrín àwọn ènìyàn yí, kí ìwọ kí ó máṣe dáwọn lẹ́bi lórí àwọn ohun wọ̀nyí. Njẹ́ ìwọ kò ha rántí àwọn àlùfã bàbá à rẹ, tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lépa láti pa bí? Njẹ́ nwọn kò ha wà nínú aginjù bí? Njẹ́ àwọn kọ́ ni nwọ́n ha jí àwọn ọmọbìnrin àwọn ará Lámánì gbé bí? Àti nísisìyí, kíyèsĩ, kí o sì sọ àwọn nkan wọ̀nyí fún ọba nã, kí òun kí ó lè sọ ọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, kí inú nwọn kí ó lè rọ̀ sí wa; nítorítí kíyèsĩ, nwọ́n ti ngbáradì fún ìgbógun ti wa; sì kíyèsĩ, àwa kò pọ̀ mọ́. Sì kíyèsĩ, nwọn yíò wá pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ọmọ ogun nwọn; àti láìjẹ́wípé ọba tù nwọ́n nínú sí wa, àwa yíò parun. Nítorítí njẹ́ ọ̀rọ̀ Ábínádì kò ha ṣẹ bí, èyítí ó sọtẹ́lẹ̀ sí wa—gbogbo èyí nítorítí àwa ṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Olúwa, kí àwa sì yípadà kúrò nínú àìṣedẽdé? Àti nísisìyí ẹ jẹ́ kí a rọ ọba, kí a sì pa májẹ̀mú èyítí a ti dá mọ́; nítorítí ó sàn kí àwa wà nínú oko-ẹrú ju kí a pàdánù ẹ̀mí wa; nítorínã, ẹ jẹ́ kí àwa fi òpin sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Àti nísisìyí Límháì wí fún ọba nã nípa gbogbo ohun nípa bàbá rẹ̀, àti àwọn àlùfã tí nwọ́n ti sálọ sínú aginjù, ó sì dá nwọn lẹ́bi fún gbígbé lọ tí nwọ́n gbé àwọn ọmọbìnrin nwọn lọ. Ó sì ṣe, tí inú ọba nã rọ̀ sí àwọn ènìyàn nã; ó sì wí fún nwọn pé: Ẹ jẹ́ kí a jáde lọ bá àwọn ènìyàn mi, láìmú ohun-ìjà dání; mo sì búra fún nyín, pẹ̀lú ìbúra wípé àwọn ènìyàn mi kò ní pa àwọn ènìyàn rẹ. Ó sì ṣe tí nwọ́n tẹ̀lé ọba nã, tí nwọ́n sì jáde lọ, láìmú ohun-ìjà dání, lọ pàdé àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí nwọ́n pàdé àwọn ará Lámánì; ọba àwọn ará Lámánì sì tẹríba níwájú nwọn, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ará Límháì. Nígbàtí àwọn ará Lámánì sì rí àwọn ará Límháì, pé nwọn kò ní ohun-ìjà dání, nwọ́n ṣãnú fún nwọn, inú nwọn sì rọ̀ sí nwọn, nwọ́n sì padà pẹ̀lú ọba nwọn sí ilẹ̀ nwọn ní àlãfíà. 21 Àwọn ará Lámánì kọlũ àwọn ènìyàn Límháì, nwọ́n s ì ṣẹ́gun nwọn—Àwọn ènìyàn Límháì bá Ámọ́nì pàdé, a sì yí nwọn lọ́kàn padà—Nwọ́n sọ nípa àwọn àwo-ìkọsílẹ̀ ti Járẹ́dì mẹ́rìnlélógúnfún Ámọ́nì. Ní ìwọ̀n ọdún 122– 121 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí Límháì àti àwọn ènìyàn rẹ padà sí ìlú ti Nífáì, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gbé orí ilẹ̀ nã ní àlãfíà lẹ̃kan síi. Ó sì ṣe, lẹ́hìn ọjọ́ pípẹ́ tí àwọn ará Lámánì tún bẹ̀rẹ̀sí rú ìbínú nwọn sókè sí àwọn ará Nífáì, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí wá sí agbègbè àlà ilẹ́ tí ó yí nwọn ká. Nísisìyí nwọn kò pa nwọ́n, nítorí ti májẹ̀mú ti ọba nwọn ti dá pẹ̀lú Límháì; ṣùgbọ́n nwọn a máa gbá nwọn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́, nwọ́n sì nfi ipá àti agbára bá nwọn lò; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gbé ẹrù wúwo lé nwọn lẹ́hìn, nwọ́n sì ndà nwọ́n síwájú bí odi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́— Bẹ̃ni, a ṣe àwọn ohun wọ̀nyí kí ọ̀rọ̀ Olúwa lè ṣẹ. Àti nísisìyí ìjìyà àwọn ará Nífáì pọ̀ jọjọ, kò sì sí ọ̀nà tí nwọ́n fi lè gba ara nwọn kúrò lọ́wọ́ nwọn, nítorítí àwọn ará Lámánì ti yí nwọn ká ní gbogbo ìhà. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí kùn sí ọba nítorí ti ìjìyà nwọn; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí wá ọ̀nà àti kọlũ nwọ́n ní ogun. Nwọ́n sì ni ọba nã lára púpọ̀ pẹ̀lú ìráhùn nwọn; nítorínã ó gbà nwọ́n lãyè kí nwọ́n ṣe èyí tí ó tẹ́ nwọn lọ́run. Nwọ́n sì tún kó ara nwọn jọ, nwọ́n gbé ìhámọ́ra nwọn wọ̀, nwọ́n sì kọjá lọ dojúkọ àwọn ará Lámánì, láti lé nwọn jáde kúrò lórí ilẹ̀ nwọn. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì lù nwọ́n, nwọ́n sì dá nwọn padà, nwọ́n sì pa púpọ̀ nínú nwọn. Àti nísisìyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀fọ̀ àti ohùn-réré ẹkún ni ó wà lãrín àwọn ará Límháì, opó nṣọ̀fọ̀ ọkọ rẹ̀, ọmọkùnrin pẹ̀lú ọmọbìnrin nṣọ̀fọ̀ bàbá nwọn, àti arákùnrin fún arákùnrin nwọn. Nísisìyí àwọn opó pọ̀ púpọ̀ ní ilẹ̀ nã, nwọ́n sì kígbe rara láti ọjọ́ dé ọjọ́, nítorítí ìbẹ̀rù àwọn ará Lámánì ti bò nwọ́n. Ó sì ṣe tí igbe nwọn àìlópin rú ọkàn àwọn ènìyàn Límháì yókù sókè sí ìbínú sí àwọn ará Lámánì; nwọ́n sì tún lọ sí ógun, ṣùgbọ́n nwọ́n dá nwọn padà lẹ̃kan síi, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àdánù. Bẹ̃ni nwọ́n tún lọ, àní ní ìgbà kẹ́ta, nwọ́n sì tún pàdánù bákannã; àwọn tí nwọn kò sì pa tún padà sí inú ìlú ti Nífáì. Nwọ́n sì rẹ ara nwọn sílẹ̀, àní búrú-búrú, nwọ́n jọ̀wọ́ ara nwọn sílẹ̀ fún àjàgà oko-ẹrú, nwọ́n jọ̀wọ́ ara nwọn fún ìfìyàjẹ, àti fún dídà sí ìhín àti sí ọ̀hún, àti ìgbé ẹrù wúwo lórí, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú àwọn ọ̀tá nwọn. Nwọ́n sì rẹ ara nwọn sílẹ̀ àní nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrẹ̀lẹ̀; nwọ́n sì kígbe pe Ọlọ́run gidigidi; bẹ̃ni, àní ní ọjọ́ gbogbo ni nwọ́n kígbe pe Ọlọ́run nwọn pé kí ó gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìpọ́njú nwọn. Àti nísisìyí, Olúwa lọ́ra láti gbọ́ igbe nwọn nítorí àìṣedẽde nwọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa gbọ́ igbe nwọn, ó sì bẹ̀rẹ̀sí mú ọkàn àwọn ará Lámánì rọ̀, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí dẹ àjàgà nwọn; síbẹ̀, Olúwa kò ì tĩ kà á sí ọgbọ́n láti yọ nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú. Ó sì ṣe, tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣe rere lórí ilẹ̀ nã, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gbin ọkà púpọ̀púpọ̀, nwọ́n sì ntọ́ agbo-ẹran, àti ọ̀wọ́-ẹran ọ̀sìn, tí ebi kò sì pa nwọ́n. Nísisìyí àwọn obìnrin pọ̀ púpọ̀, ju àwọn ọkùnrin; nítorínã, Límháì ọba pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn ọkùnrin máa ṣe ìrànlọ́wọ́ àwọn opó àti ọmọ nwọn, kí nwọn má bã parun pẹ̀lú ebi; èyí ni nwọ́n sì ṣe nítorítí àwọn tí nwọ́n ti pa nínú nwọn pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nísisìyí àwọn ará Límháì sì dúró papọ̀ ní ọ̀kan gẹ́gẹ́bí ó ti ṣeéṣe fún nwọn, nwọ́n sì nkó àwọn ọkà nwọn pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ẹran nwọn pamọ́; Ọba pãpã kò gbóyà tó láti wà ní ẹ̀hìn odi ìlú, láìjẹ́wípé òun mú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ní ìbẹ̀rù pé ní ọ̀nà kan, òun lè bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Lámánì. Ó sì mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ máa ṣọ́ ìlú nã yíká kiri, pé nípa ọ̀nà kan, nwọn lè mú àwọn àlùfã nnì tí nwọ́n ti sá lọ sínú aginjù, tí nwọ́n ti jí àwọn ọmọbìnrin Lámánì gbé, àti tí nwọ́n ti ṣeé tí ìparun nlá ti wá sórí nwọn. Nítorítí nwọ́n fẹ́ láti mú nwọn kí nwọ́n lè fi ìyà jẹ nwọ́n; nítorítí nwọ́n wọ inú ìlú ti Nífáì ní àṣálẹ́, nwọ́n sì jí gbogbo ọkà nwọn gbé àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan olówó iyebíye nwọn; nítorínã, nwọ́n ba pamọ́ dè nwọ́n. Ó sì ṣe, tí ìrùkèrúdò dé òpin lãrín àwọn ará Lámánì àti àwọn ènìyàn Límháì, àní títí dé ìgbà tí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi wá sí ilẹ̀ nã. Nígbàtí ọba sì wà ní ẹ̀hìn odi ìlú pẹ̀lú ẹ̀ṣọ́ rẹ, ó ṣe ìwárí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀; ó sì fi nwọ́n pe àlùfã Nóà, nítorínã ó pàṣẹ pé kí a mú nwọn, kí a sì dè nwọ́n, kí a sì sọ nwọ́n sínú tũbú. Tí nwọ́n bá sì jẹ́ àlùfã Nóà, ìbá ti pàṣẹ pé kí a pa nwọ́n. Ṣùgbọ́n, nígbàtí ó rí i pé nwọn kìi ṣe é, ṣùgbọ́n pé arákùnrin òun ni nwọn íṣe, tí nwọ́n sì wá láti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ó kún fún ayọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nísisìyí ọba Límháì, kí Ámọ́nì tó dé, ti rán àwọn arákùnrin díẹ̀ láti lọ ṣe àwárí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; ṣùgbọ́n nwọn kò ríi, nwọ́n sì sọnù nínú aginjù. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n rí ilẹ̀ kan tí ènìyàn ti gbé inú rẹ̀ rí; bẹ̃ni ilẹ̀ tí egungun gbígbẹ borí rẹ̀; bẹ̃ni, ilẹ̀ tí ènìyàn ti gbé inú rẹ́ rí, tí nwọ́n sì ti parun; nítorítí nwọ́n sì fií pe ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nwọ́n padà sí ilẹ̀ Nífáì, tí nwọ́n sì ti dé ìhà ilẹ̀ nã ní ọjọ́ díẹ̀ ṣãjú bíbọ̀ Ámmónì. Nwọ́n sì gbé ìwé ìràntí kan wá, àní ìwé ìràntí àwọn ènìyàn nã tí nwọ́n rí egungun nwọn; a sì fín in sórí àwo irin àìpò. Àti nísisìyí Límháì sì tún kún fún ayọ̀ nígbàtí ó gbọ́ láti ẹnu Ámọ́nì pé ọba Mòsíà ní ẹ̀bùn kan láti ọwọ́ Ọlọ́run, èyítí ó fi lè túmọ̀ irú fífín bẹ̃; bẹ̃ni, Ámọ́nì nã sì yọ̀. Síbẹ̀, Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kún fún ìrora-ọkàn nítorípé púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin nwọn ni a ti pa; Àti pẹ̀lú pé ọba Nóà àti àwọn àlùfã rẹ̀ ti jẹ́ kí àwọn ènìyàn nã dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ àti àìṣedẽdé sí Ọlọ́run; nwọ́n sì ṣọ̀fọ̀ lórí ikú Ábínádì; àti pẹ̀lú jíjádelọ Álmà àti àwọn ènìyàn tí ó bá a lọ, tí nwọ́n ti kó ìjọ Ọlọ́run jọ nípasẹ̀ ipá àti agbára Ọlọ́run, àti ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ ti Ábínádì ti sọ. Bẹ̃ni nwọ́n ṣọ̀fọ̀ fún lílọ tí nwọ́n lọ, nítorítí nwọn kò mọ́ ibi tí nwọ́n sálọ sí. Nísisìyí, nwọ́n níìfẹ́ láti darapọ̀ mọ́ nwọn, nítorítí àwọn pãpã ti wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run láti sìn ín àti láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́. Àti nísisìyí láti ìgbàtí Ámọ́nì ti dé, ọba Límháì pãpã ti bá Ọlọ́run dá májẹ̀mú, àti púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú, láti sìn ín, àti láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́. Ó sì ṣe tí ọba Límháì pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìfẹ́ fún ìrìbọmi; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan ní ilẹ̀ nã tí ó ní àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ámọ́nì sì kọ̀ láti ṣe eleyĩ, nítorípé ó ka ara rẹ̀ kún ìránṣẹ́ aláìpé. Nítorínã, nwọn kò kó ara nwọn jọ fún ìjọ ní ìgbà nã, nwọ́n sì dúró de Ẹ̀mí Olúwa. Nísisìyí nwọ́n ní ìfẹ́ láti dà bí Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, tí nwọ́n ti sá lọ sínú aginjù. Nwọ́n ní ìfẹ́ kí a rì nwọn bọmi, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí àti ìjẹ̃rí pé nwọ́n ti jọ̀wọ́ ara nwọn fún sísin Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn nwọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n sún àkókò nã síwájú; àkọsílẹ̀ ìrìbọmi nwọn ni a ó sọ láìpẹ́. Àti nísisìyí, gbogbo èrò Ámọ́nì àti àwọn ènìyàn rẹ̀, pẹ̀lú ọba Límháì àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ni pé kí nwọ́n gba ara nwọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì àti kúrò nínú oko-ẹrú. 22 A gbèrò ọ̀nà fún àwọn ènìyàn nã láti yọ kúrò nínú oko-ẹrú àwọn ará Lámánì—A mú kí àwọn ará Lámánì mútípara—Àwọn ènìyàn nã yọ kúrò, nwọ́n padà sí Sarahẹ́múlà, nwọ́n sì di ènìyàn ìlú lábẹ́ ọba Mòsíà. Ní ìwọ̀n ọdún 121 sí 120 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ó sì ṣe, tí Ámọ́nì àti ọba Límháì bẹ̀rẹ̀síi wá ìdí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn nã bí nwọn ó ṣe gba ara nwọn kúrò nínú oko-ẹrú; àti pẹ̀lú nwọn pàṣẹ kí gbogbo ènìyàn kó ara nwọn jọ; eleyĩ ni nwọ́n ṣe kí nwọn kí ó lè mọ ohùn àwọn ènìyàn nã nípa ọ̀rọ̀ nã. Ó sì ṣe tí nwọn kò rí ọ̀nà tí nwọ́n lè gbà yọ ara nwọn kúrò nínú oko-ẹrú, àfi tí nwọ́n bá kó àwọn obìnrin nwọn, àti àwọn ọmọ, àti agbo àti ọ̀wọ́-ẹran, àti àgọ́ nwọn, kí nwọ́n sì kọjá lọ sínú aginjù; nítorítí àwọn ará Lámánì ti pọ̀ tó bẹ̃ tí kò sí ọ̀nà tí àwọn ènìyàn Límháì lè dojú ìjà kọ nwọ́n, tí nwọ́n rò pé àwọn lè gba ara nwọn sílẹ̀ nínú oko-ẹrú pẹ̀lú idà. Nísisìyí, ó sì ṣe tí Gídéónì kọjá lọ ó sì dúró níwájú ọba, ó sì wí fún un pé: Nísisìyí, A! ọba, ìwọ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi títí dé ìhín, ní ìgbà púpọ̀ tí àwa nbá àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì jà. Àti nísisìyí, A! ọba, bí ìwọ kò bá kà mí kún ọmọ-ọ̀dọ̀ aláìlérè, tàbí tí ìwọ bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi títí dé ìhín, bí ó ti wù kí ó kéré tó, tí nwọ́n sì wúlò fún ọ, bẹ̃ nã sì ni èmi fẹ́ kí ìwọ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi ní ìgbà yĩ, èmi yíò sì jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ, èmi ó sì gba àwọn ènìyàn yí nínú oko-ẹrú. Ọba sì gbà á lãyè láti sọ̀rọ̀. Gídéónì sì wí fún un pé: Kíyèsí ọ̀nà tí ó wà lẹ́hìn, ní ipa odi tí ó wà lẹ́hìn, ní ìhà tí ówà lẹ́hìn ìlú. Àwọn ará Lámánì tàbí àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn ará Lámánì, a máa mutí yó lálẹ́; nítorínã jẹ́ kí a ṣe ìkéde lãrín gbogbo àwọn ènìyàn yí, pé kí nwọ́n kó agbo àti ọ̀wọ́ ẹran nwọn jọ, kí nwọ́n sì dà nwọ́n lọ sínú aginjù ní àṣálẹ́. Èmi yíò sì ṣe gẹ́gẹ́bí àṣẹ rẹ, èmi ó san owó-òde ìkẹhìn ní ti wáìnì fún àwọn ará Lámánì, nwọn ó sì mutí para; àwa yíò sì gba ọ̀nà ìkọ̀kọ̀ ní ìkọjá èyítí ó wà ní apá òsì ibùdó nwọn, nígbàtí nwọn yíò ti mutípara, tí nwọn yíò sì ti sùn lọ. Báyĩ sì ni àwa yíò jáde kúrò pẹ̀lú àwọn obìnrin wa àti àwọn ọmọ wa, àwọn agbo ẹran wa àti àwọn ọ̀wọ́ ohun ọ̀sìn wa lọ sínú aginjù; àwa yíò sì rin ìrìn-àjò yípo ilẹ̀ ti Ṣílómù. Ó sì ṣe, tí ọba nã gbọ́ran sí Gídéónì lẹ́nu. Límháì ọba sì pàṣẹ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ kó àwọn agbo ẹran nwọn jọ; ó sì fi owó-òde ọtí wáìnì ránṣẹ́ sí àwọn ará Lámánì; òun sì fi ọtí wáìnì púpọ̀ ránṣẹ́ gẹ́gẹ́bí ọrẹ sí nwọn; nwọ́n sì mu ọtí wáìnì nã, èyítí ọba Límháì fi ránṣẹ́ sí nwọn ní ámupara. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn ọba Límháì sì jáde kúrò ní àṣálẹ́ lọ sínú aginjù pẹ̀lú agbo ẹran nwọn àti ọ̀wọ́ ohun ọ̀sìn nwọn, nwọ́n sì yípo ilẹ̀ Ṣílómù, nínú aginjù, nwọ́n sì yí ẹsẹ̀ padà sí ìhà ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ndarí nwọn. Nwọ́n sì ti mú gbogbo wúrà, àti turàrí pẹ̀lú ohun ìní nwọn olówó-iyebíye, tí nwọ́n lè gbé, àti gbogbo ohun-ìpèsè nwọn pẹ̀lú nwọn, kọjá lọ sínú aginjù; nwọ́n sì tẹ̀síwájú ní ìrìnàjò nwọn. Lẹ́hìn tí nwọ́n sì ti wà nínú aginjù fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, nwọ́n dé ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nwọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Mòsíà, nwọ́n sì wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀. Ó sì ṣe, tí Mòsíà gbà nwọn tayọ̀-tayọ̀; ó sì tún gba ìwé ìrántí nwọn, àti ìwé-ìrántí èyítí àwọn ará Límháì ṣe àwárí rẹ̀. Àti nísisìyí, ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Lámánì ti ní òye pé àwọn ènìyàn Límháì ti jáde kúrò ní ilẹ̀ nã ní àṣálẹ́, nwọ́n rán àwọn ọmọ ogun sínú aginjù láti lé nwọn bá; Nígbàtí nwọ́n sì lé nwọn fún ọjọ́ méjì, nwọn kò lè tọ ipasẹ̀ ọ̀nà tí nwọ́n gbà mọ; nítorínã nwọ́n sọnù sínú aginjù. Ìtàn nípa Álmà àti àwọn ènìyàn Olúwa, àwọn ẹni tí a lé sínú aginjù nípa ọwọ́ àwọn ènìyàn Ọba Nóà. Èyítí a kọ sí àwọn orí 23 àti 24. 23 Álmá kọ̀ láti jẹ́ ọba—Ó sìn gẹ́gẹ́bí olórí àlúfã—Olúwa bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí, àwọn ará Lámánì sì ṣẹ́gun ilẹ̀ ti Hẹ́lámì—Ámúlónì, olórí àwọn àlùfã búburú ti Ọba Nóà, ṣe ìjọba lábẹ́ àkóso ìjọba àwọn ará Lámánì. Ní ìwọ̀n ọdún 145 sí 121 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí Álmà, lẹ́hìn tí Olúwa ti kìlọ̀ fún un pé àwọn ọmọ ogun ọba Nóà yíò kọlù nwọ́n, àti lẹ́hìn tí ó ti sọ ọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorínã, nwọn kó ọ̀wọ́ ohun ọ̀sìn nwọn, nwọ́n sì mú àwọn wóró irúgbìn nwọn, nwọ́n sìkọjá lọ sínú aginjù ṣíwájú ọmọ ogun ọba Nóà. Olúwa sì fún nwọn ní agbára, tí àwọn ènìyàn ọba Nóà kò lè bá nwọn láti pa nwọ́n run. Nwọ́n sì sá fún ìrìn-àjò ọjọ́ mẹ́jọ nínú aginjù. Nwọ́n sì dé ilẹ̀ kan, bẹ̃ni, àní ilẹ̀ kan tí ó lẹ́wà púpọ̀ tí ó sì wuni, ilẹ̀ tí ó ní omi tí ó mọ́. Nwọ́n sì pàgọ́ nwọn, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síi dáko, nwọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé; bẹ̃ni, nwọ́n lãpọn, nwọ́n sì nṣiṣẹ́ púpọ̀púpọ̀. Àwọn ènìyàn nã sì ní ìfẹ́ kí Álmà jẹ́ ọba nwọn, nítorítí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìfẹ́ ẹ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó wí fún nwọn pé: Kíyèsĩ, kò tọ́ kí a ní ọba; nítorí báyĩ ni Olúwa wí: Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ gbé ẹnìkan ga ju ẹlòmiràn, tàbí ẹnìkan kò gbọ́dọ̀ rò pé òun ga ju ẹlòmíràn lọ; nítorínã mo wí fún un yín pé kò tọ́ kí ẹ̀yin ní ọba. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, tí ó bá ṣeéṣe kí ẹ̀yin ní ẹnití ó tọ́ láti jẹ́ àwọn ọba yín nígbà-gbogbo, yíò dára fún yín láti ní ọba. Ṣùgbọ́n ẹ rántí àìṣedẽdé ọba Nóà, àti àwọn àlùfã rẹ̀; èmi pãpã kó sínú ìgbèkùn, tí mo sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ ìríra lójú Olúwa, lórí èyítí èmi ṣe ìrònúpìwàdà tí ó múná. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú, Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì gbọ́ àdúrà mi, ó sì ti fi mí ṣe ohun èlò lọ́wọ́ rẹ fún mímú ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín wá sínú ìmọ̀ ọ̀títọ́ ọ rẹ̀. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nínú èyí èmi kò ṣògo, nítorítí kò tọ́ fún mi kí èmi kí ó yin ara mi. Àti nísisìyí mo wí fún yín, ẹ̀yin ti wà nínú ìnilára ọba Nóà, ẹ̀yin sì ti wà nínú oko-ẹrú rẹ àti ti àwọn àlùfã rẹ̀, nwọn sì ti mú yín ṣe àìṣedẽdé; nítorínã, ẹ̀yin wà nínú ìdè àìṣedẽdé. Àti nísisìyí, nítorítí a ti gbà yín kúrò nínú àwọn ìdè wọnyí nípa agbára Ọlọ́run; bẹ̃ni, àní kúrò lọ́wọ́ ọba Nóà àti àwọn ènìyàn rẹ, àti kúrò nínú ìdè àìṣedẽdé pẹ̀lú, bẹ̃ni èmi sì ní ìfẹ́ kí ẹ̀yin kí ó dúró ṣinṣin nínú òmìnira yĩ, nínú èyítí a ti sọ yín di òmìnira, kí ẹ̀yin má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé ẹnìkẹ́ni kí ó jọba lórí i yín. Àti pẹ̀lú, ẹ máṣe gbẹ́kẹ̀lé ẹnìkẹ́ni láti jẹ́ olùkọ́ yín tàbí àlùfã yín, àfi tí ó bá jẹ́ ẹni Ọlọ́run, tí ó nrìn ní ọ̀nà rẹ, tí ó sì npa àwọn òfin rẹ̀ mọ́. Báyĩ ni Álmà kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀, pé kí olúkúlùkù fẹ́ràn ọmọnìkéjì rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ara rẹ̀, kí asọ̀ máṣe wà lãrín nwọn. Àti nísisìyí, Álmà ni olórí àlùfã nwọn, ẹnití íṣe olùdásílẹ̀ ìjọ nwọn. Ó sì ṣe, tí ẹnìkẹ́ni kò gba àṣẹ láti wãsù tàbí kọ́ni-lẹ́kọ̣́, àfi nípasẹ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ Ọlọ́run. Nítorínã, ó ya gbogbo àwọn àlùfã nwọn àti àwọn olùkọ́ni nwọn sí mímọ́; kò sì sí ẹnìkan tí a yà sí mímọ́ bíkòṣe ẹnití ó tọ́. Nítorínã nwọ́n ṣọ́ àwọn ènìyàn nwọn, nwọ́n sì bọ́ nwọn pẹ̀lú ohun tĩ ṣe ti òdodo. Ó sì ṣe tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ilẹ̀ nã; nwọ́n sì pe orúkọ ilẹ̀ nã ní Hẹ́lámì. Ó sì ṣe tí nwọ́n bí sĩ, tí nwọ́n sì ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ilẹ̀ ti Hẹ́lámì; nwọ́n sì kọ́ ìlú nlá kan, èyítí nwọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní ìlú-nlá Hẹ́lámì. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa rí i pé ó tọ́ láti bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí; bẹ̃ni, òun dán sũrù nwọn àti ìgbàgbọ́ nwọn wò. Bíótilẹ̀ríbẹ̃—ẹnìkẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e, òun ni a o gbé sókè ní ọjọ́ ìkẹ́hìn. Bẹ̃ni, báyĩ ni ó sì rí fún àwọn ènìyàn yí. Nítorí kíyèsĩ, èmi yíò fihàn yín pé a mú nwọn wá sínú oko-ẹrú, kò sì sí ẹni nã tí ó lè gbà nwọ́n àfi Olúwa Ọlọ́run nwọn, bẹ̃ni, àní Ọlọ́run Ábráhámù àti Ísãkì àti ti Jákọ́bù. Ó sì ṣe, tí ó gbà nwọ́n, ó sì fi agbára nlá hàn nwọ́n, púpọ̀ sì ni àjọyọ̀ nwọn. Nítorí kíyèsĩ, ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n wà ní ilẹ̀ ti Hẹ́lámì, bẹ̃ni, nínú olú-ìlú ilẹ̀ Hẹ́lámì, tí nwọ́n ndáko yíká, kíyèsĩ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì wà ní ãlà ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe nísisìyí, tí àwọn arákùnrin Álmà sá lọ kúrò nínú oko nwọn, tí nwọ́n sì kó ara nwọn jọ nínú olú-ìlú ti Hẹ́lámì; ẹ̀rù sì bà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ìfarahàn àwọn ará Lámánì. Ṣùgbọ́n Álmà kọjá lọ ó sì dúró lãrín nwọn, ó sì gbà nwọ́n níyànjú pé kí nwọ́n máṣe bẹ̀rù, ṣùgbọ́n pé kí nwọn rántí Olúwa Ọlọ́run nwọn, òun yíò sì gbà nwọ́n. Nítorínã nwọ́n mú ẹ̀rù nwọn kúrò, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí képe Olúwa, pé kí ó lè mú ọkàn àwọn ará Lámánì rọ̀, pé kí nwọ́n dá ẹ̀mí nwọn sí, àti àwọn ìyàwó nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn. Ó sì ṣe, Olúwa sì mú kí ọkàn àwọn ará Lámánì rọ̀. Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sì kọjá lọ, nwọ́n sì jọ̀wọ́ ara nwọn sílẹ̀ lé nwọn lọ́wọ́; àwọn ará Lámánì sì ṣe ìkógun ilẹ̀ ti Hẹ́lámì. Báyĩ àwọn ọmọ ogun àwọn Lámánì, tí nwọ́n ti sá tẹ̀lé àwọn ará ọba Límháì, ti sọnù nínú aginjù fún ọjọ́ púpọ̀. Sì kíyèsĩ, nwọ́n ti rí àwọn àlùfã ọba Nóà, ní ibìkan tí nwọn npè ní Ámúlónì; nwọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìkógun ilẹ̀ Ámúlónì nwọ́n sì ndáko. Nísisìyí orúkọ olórí àwọn àlùfã nã ni í ṣe Ámúlónì. Ó sì ṣe tí Ámúlónì ṣìpẹ̀ pẹ̀lú àwọn ará Lámánì; ó sì tún rán àwọn ìyàwó nwọn, tí nwọn jẹ́ ọmọbìnrin àwọn ará Lámánì, kí nwọn ṣìpẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn, pé kí nwọ́n máṣe pa àwọn ọkọ nwọn. Àwọn ará Lámánì sì ṣãnú fún Ámúlónì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, nwọn kò sì pa nwọ́n, nítorí àwọn ìyàwó nwọn. Ámúlónì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ sì darapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì nrin ìrìn-àjò nínú aginjù, tí nwọ́n nwá ilẹ̀ ti Nífáì, nígbàtí nwọ́n sì ṣe àwárí ilẹ̀ ti Hẹ́lámì, èyítí Álmà pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣe ìkógun rẹ̀. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì ṣe ìpinnu fún Álmà pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, wípé bí nwọ́n bá lè fi ọ̀nà hàn nwọ́n, èyítí ó lọ sí ilẹ̀ ti Nífáì, nwọn yíò jọ̀wọ́ ẹ̀mí nwọn àti òmìnira nwọn fún nwọ́n. Ṣùgbọ́n lẹ́hìn tí Álmà ti fi ọ̀nà tí ó lọ sí ilẹ̀ ti Nífáì hàn nwọ́n tán, àwọn ará Lámánì kùnà láti pa ìpinnu nwọn mọ́; ṣùgbọ́n nwọ́n fi àwọn ìṣọ́ yí ilẹ̀ Hẹ́lámì ká kiri, sí orí Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀. Àwọn tí ó kù nínú nwọn sì lọ sínú ilẹ̀ ti Nífáì; òmíràn nínú nwọn padà sí ilẹ̀ Hẹ́lámì, nwọ́n sì mú wá pẹ̀lú nwọn àwọn ìyàwó pẹ̀lú àwọn ọmọ àwọn ìṣọ́ tí nwọ́n kù lẹ́hìn. Ọba àwọn ará Lámánì sì ti gbà kí Ámúlónì jẹ́ ọba àti alákọ́so fún àwọn ènìyàn rẹ̀, tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Hẹ́lámì; bíótilẹ̀ríbẹ̃ pé kí yíò ní àṣẹ láti ṣe ohunkóhun tí ó lòdì sí ìfẹ́ ti ọba àwọn ará Lámánì. 24 Ámúlónì ṣe inúnibíni sí Álmà àti àwọn ènìyàn rẹ̀—A ó pa nwọ́n tí nwọ́n bá gbàdúrà—Olúwa sọ ìnira nwọn di fífúyẹ́—Ó gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú, nwọ́n sì padà sí Sarahẹ́múlà. Ní ìwọ̀n ọdún 145 sí 120 kí a tó bí Olúwa wa. Ósì ṣe tí Ámúlónì rí ojú rere gbà níwájú ọba àwọn ará Lámánì; nítorínã, ọba àwọn ará Lámánì gbà fún un pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ pé kí a yàn nwọ́n gẹ́gẹ́bí olùkọ́ni lórí àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̃ni, àní lórí àwọn ènìyàn nã tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Ṣẹ́múlónì, àti ní ilẹ̀ Ṣílómù, àti ní ilẹ̀ Ámúlónì. Nítorítí àwọn ará Lámánì ti gbà gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí; nítorínã, ọba àwọn Lámánì ti yan àwọn ọba lórí àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí. Àti nísisìyí, orúkọ ọba àwọn ará Lámánì ni Lámánì, ẹnití a sọ lórúkọ bàbá rẹ̀; nítorínã ni a ṣe pè é ni ọba Lámánì. Ó sì jẹ ọba lórí ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sì yan àwọn olúkọni nínú àwọn arákùnrin Ámúlónì, nínú gbogbo ilẹ̀ ti àwọn ènìyàn rẹ̀ ti gbà; báyĩ sì ni èdè Nífáì ṣe di kíkọ́ lãrín àwọn ará Lámánì. Nwọ́n sì jẹ́ ènìyàn tí nwọ́n ní ìfẹ́ ara nwọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọn kò mọ́ Ọlọ́run; bẹ̃ni àwọn arákùnrin Ámúlónì kò kọ́ nwọn ní ohunkóhun nípa Olúwa Ọlọ́run nwọn, tàbí òfin Mósè; tàbí kí nwọ́n kọ́ nwọn ni ọ̀rọ̀ Ábínádì; Ṣùgbọ́n nwọn kọ́ nwọn kí nwọ́n ṣe ìkọsílẹ̀ ìwé ìrántí nwọn, kí nwọ́n sì kọ nwọn láti ọkàn dé òmíràn. Báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀ sĩ pọ̀ sĩ ní ọrọ̀, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe òwò pẹ̀lú ara nwọn, nwọ́n sì pọ̀ síi ní agbára, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sĩ di alárẽkérekè ati ọlọ́gbọ́n ènìyàn, nwọ́n sì gbọ́n ọgbọ́n ayé, bẹ̃ni, nwọ́n j ẹ́ ọlọ́gbọ́n àrékérekè púpọ̀púpọ̀, tí nwọ́n sì ní inú dídùn sí onírurú ìwà búburú àti ìkógun, àfi tí ó bá jẹ́ lãrín àwọn arákùnrin nwọn. Àti nísisìyí ó sì ṣe, tí Ámúlónì bẹ̀rẹ̀ sĩ pàṣẹ lé Álmà pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ lórí, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sĩ ṣe inúnibíni rẹ̀, tí ó sì mú kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ nwọn. Nítorítí Ámúlónì mọ́ Álmà, pé òun jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àlùfã ọba, àti pé òun ni ẹnití ó gba ọ̀rọ̀ Ábínádì gbọ́, tí a sì lé e kúrò níwájú ọba, nítorínã, ó bínú síi; nítorítí ó wà lábẹ́ àkóso ọba Lámánì, síbẹ̀, ó ní àṣẹ lórí nwọn, ó sì mú nwọn ṣiṣẹ́, òun sì yan akóni-ṣiṣẹ́ lé nwọn lórí. Ó sì ṣe tí ìpọ́njú nwọn pọ̀ tóbẹ̃ gẹ́ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀ sĩ kígbe pe Ọlọ́run gidigidi. Ámúlónì sì pa á láṣẹ fún nwọn pé kí nwọ́n dẹ́kun igbe wọn; òun sì yan ìṣọ́ lé nwọn, pé ẹnìkẹ́ni tí a bá rí tí ó nképe Ọlọ́run yíò di pípa. Álmà àtí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì gbé ohùn nwọn sókè sí Olúwa Ọlọ́run nwọn, ṣùgbọ́n nwọ́n gbé gbogbo ọkàn nwọn sókè síi; òun sì mọ gbogbo èrò ọkàn nwọn. Ó sì ṣe tí ohùn Olúwa tọ́ nwọ́n wá nínú ìpọ́njú nwọn, tí ó wípé: Ẹ gbé orí i yín sókè, kí ẹ sì tújúká, nítorítí èmi mọ́ májẹ̀mú tí ẹ̀yin ti dá pẹ̀lú mi; èmi yíò sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi, èmi yíò sì gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú. Èmi yíò sì dẹ ìnilára tí a gbé lée yín ní éjìká, pé ẹ̀yin kò lè mọ̀ ọ́ lórí ẹ̀hìn nyín, bí ẹ̀yin tilẹ̀ wà nínú oko-ẹrú; èyí yíi ni èmi yíò ṣe kí ẹ̀yin kí ó lè dúró gẹ́gẹ́bí ẹlẹ̃rí fún mi ní ọjọ́ tí nbọ̀, àti kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ dájúdájú pé èmi, Olúwa Ọlọ́run nbẹ àwọn ènìyàn mi wò nínú ìpọ́njú nwọn. Àti nísisìyí ó ṣì ṣe tí ìnira tí a gbé ru Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ di fífúyẹ́; bẹ̃ni, Olúwa fún nwọn ní okun kí nwọ́n lè gbé ẹrù nã pẹ̀lú ìrọ̀rùn, nwọ́n sì jọ̀wọ́ ara sílẹ̀ fún ìfẹ́ Olúwa pẹ̀lú ọ̀yàyà àti sũrù. Ó sì ṣe tí ìgbàgbọ́ àti sũrù nwọn tóbi púpọ̀, tí ohùn Olúwa tún tọ̀ nwọ́n wá, tí ó wípé: Ẹ tújúká, nítorítí ní ọjọ́ ọ̀la, èmi yíò gbà yín kúrò nínú oko-ẹrú. Ó sì wí fún Álmà pé: Ìwọ yíò ṣíwájú àwọn ènìyàn yí, èmi yíò sì bã yín lọ èmi yíò sì gba àwọn ènìyàn yí kúrò nínú oko-ẹrú. Nísisìyí ó sì ṣe tí Álmà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àṣalẹ́ kó àwọn ọwọ́ ohun ọ̀sìn nwọn jọ, pẹ̀lú àwọn irú hóró èso nwọn; bẹ̃ni, àní ní gbogbo alẹ́ ni nwọn fi nkó àwọn ọ̀wọ́ ohun ọ̀sìn nwọn jọ. Àti ní òwúrọ̀, Olúwa mú kí ọ́run ìwọra kun àwọn ara Lámánì, bẹ̃ni, gbogbo àwọn akóni-ṣiṣẹ́ nwọn sì sùn lọ fọnfọn. Álmà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ sì kọjá lọ sínú aginjù; nígbàtí nwọ́n sì ti rin ìrìnàjò ní gbogbo ọjọ́ nã, nwọ́n pàgọ́ sínú àfonífojì kan, nwọ́n sì pe orúkọ àfonífojì nã ní Álmà, nítorítí ó ṣíwájú nwọn nínú aginjù. Bẹ̃ni, nínú àfonífojì Álmà ní nwọ́n sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítórítí ó ti ṣãnú fún nwọn, ó sì ti mú ìnira nwọn rọrùn, tí ó sì ti gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú; nítorítí nwọ́n wà nínú oko-ẹrú, kò sì sí ẹnití ó lè gbà nwọ́n àfi Olúwa Ọlọ́run nwọn. Nwọ́n sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, bẹ̃ni, gbogbo ọkùnrin nwọn, àti gbogbo obìnrin nwọn, àti gbogbo àwọn ọmọ nwọn tí ó lè sọ̀rọ̀ ni ó gbé ohùn nwọn sókè fún ìyìn Ọlọ́run nwọn. Àti nísisìyí Olúwa wí fún Álmà pé: Ṣe kánkán, kí o sì jáde pẹ̀lú àwọn ènìyàn yí kúrò nínú ilẹ̀ yí, nítorítí àwọn ará Lámánì ti jí nwọ́n sì nlée yín; nítorínã jáde kúrò ní ilẹ̀ yí, èmi yíò sì dá àwọn ará Lámánì dúró nínú àfonífojì yí, kí nwọn kí ó má lè sá tẹ̀lé àwọn ènìyàn yí. Ó sì ṣe tí nwọ́n jáde kúrò ní àfonífojì nã, tí nwọ́n sì tẹ̀síwájú nínú ìrìn-àjò nwọn sínú aginjù. Lẹhìn tí nwọ́n sì ti wà nínú aginjù fún ọjọ́ méjìlá, nwọ́n déinú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; ọba Mòsíà sì tún gbà nwọ́n tayọ̀tayọ̀. 25 Àwọn àtẹ̀lé Múlẹ́kì tí nwọ́n wà ní Sarahẹ́múlà di ará Nífáì—Nwọ́n kọ́ nípa àwọn ará Àlmà, àti nípa Sẹ́nífù—Álmà rì Límháì bọmi pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀—Mòsíà fi àṣẹ fún Álmà fún ìdásílẹ̀ Ìjọ-Ọlọ́run. Ní ìwọ̀n ọdún 120 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ọba Mòsíà sì mú kí a kó àwọn ènìyàn nã jọ. Nísisìyí àwọn ọmọ Nífáì kò pọ̀ púpọ̀, tàbí pé àwọn tí nwọ́n jẹ́ àtẹ̀lé Nífáì, kò tó bí àwọn ará Sarahẹ́múlà ṣe pọ̀ tó, tí nwọn íṣe ọmọ-àtẹ̀lé Múlẹ́kì, àti àwọn tí nwọ́n jáde pẹ̀lú rẹ̀ sínú aginjù. Àwọn ará Nífáì pẹ̀lú àwọn ará Sarahẹ́múlà kò sì pọ̀ tó àwọn ará Lámánì; bẹ̃ni, nwọn kò pọ̀ tó ìdásíméjì nwọn. Àti nísisìyí, a kò gbogbo àwọn ará Nífáì jọ pọ̀, àti gbogbo àwọn ará Sarahẹ́múlà pẹ̀lú, a sì kó nwọ́n jọ pọ̀ sí apá ọ̀nà méjì. Ó sì ṣe tí Mòsíà kã, tí ó sì pàṣẹ pé kí a ka ìwé ìrántí Sẹ́nífù sí àwọn ènìyàn rẹ̀; bẹ̃ni, ó ka ìwé ìrántí àwọn ará Sẹ́nífù, láti ìgbàtí nwọ́n ti kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà títí tí nwọ́n tún padà wá. Ó sì tún ka àkọsílẹ̀ nípa Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpọ́njú nwọn, láti ìgbà tí nwọ́n kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà títí dé ìgbà tí nwọ́n tún padà. Àti nísisìyí, nígbàtí Mòsíà ti parí kíka ìwé ìrántí nã, àwọn ènìyàn rẹ̀ tí nwọ́n dúró lẹ́hìn ní ilẹ̀ nã kún fún ìyanu, hã sì ṣe nwọ́n. Nítorí nwọn kò mọ́ ohun tí àwọn ìbá rò; nítorí nígbàtí nwọ́n rí àwọn tí Olúwa ti kó yọ kúrò nínú oko-ẹrú, nwọ́n kún fún ayọ̀ gidigidi. Ẹ̀wẹ̀, nígbàtí nwọ́n ronú nípa àwọn arákùnrin nwọn, èyítí àwọn ará Lámánì pa, nwọ́n kún fún ìrora-ọkàn, àní nwọ́n sọkún púpọ̀ nítọrí ìrora-ọkàn nwọn. Ẹ̀wẹ̀, nígbàtí nwọ́n ronú nípa ọ́re Ọlọ́run, àti agbára rẹ̀ èyítí ó fi gba Álmà pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì àti kúrò nínú oko-ẹrú, nwọ́n gbé ohùn nwọn sókè, nwọ́n sì fi ọpẹ́ fún Olúwa. Ẹ̀wẹ̀, nígbàtí nwọ́n ronú nípa àwọn ará Lámánì, tí nwọ́n jẹ́ arákùnrin nwọn, nípa ipò ẹ̀ṣẹ̀ àti ìbàjẹ́ nwọn, nwọ́n kún fún ìrora àti àròkàn fún àlãfíà ọkàn nwọn. Ó sì ṣe, tí àwọn tí íṣe ọmọ Ámúlónì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, tí nwọ́n ti fẹ́ aya nínú àwọn ọmọbìnrin àwọn ará Lámánì, banújẹ́ lórí ìwà àwọn bàbá nwọn, nwọn kò sì jẹ́ orúkọ àwọn bàbá nwọn mọ́, nítorínã nwọ́n gbé orúkọ Nífáì, pé kí a lè pè nwọ́n ní àwọn ọmọ Nífáì, kí a sì kà nwọ́n mọ́ àwọn tí à npè ní ará Nífáì. Àti nísisìyí gbogbo àwọn ará Sarahẹ́múlà ni a kà pẹ̀lú àwọn ará Nífáì, a sì ṣe èyí nítorípé nwọn kò gbé ìjọba lé ọwọ́ ẹnìkẹ́ni bí kò bá íṣe àtẹ̀lé Nífáì. Àti nísisìyí ó sì ṣe, nígbàtí Mòsíà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní sísọ àti kíkà sí àwọn ènìyàn nã, ó fẹ́ kí Álmà nã bá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀. Álmà sì bá nwọn sọ̀rọ̀, nígbàtí nwọ́n ti péjọ pọ̀ ní ìsọ̀ríìsọ̀rí, ó sì lọ láti ìsọ̀rí kan dé òmíràn, ó sì nwãsù sí àwọn ènìyàn fún ìrònúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀, àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa. Ó sì gba àwọn ènìyàn Límháì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, gbogbo àwọn tí a ti yọ nínú okoẹrú níyànjú, pé kí nwọ́n rántí pé Olúwa ni ó kó nwọn yọ. Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí Álmà ti kọ́ àwọn ènìyàn nã ní ohun púpọ̀, tí ó sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó bá nwọn sọ, ọba Límháì ní ìfẹ́ láti ṣe ìrìbọmi; gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ nã sì ní ìfẹ́ láti ṣe rìbọmi pẹ̀lú. Nítorínã, Álmà jáde lọ sínú omi ó sì rì nwọn bọmi; bẹ̃ni, ó rì nwọn bọmi gẹ́gẹ́bí ó ṣe ṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀ nínú omi Mọ́mọ́nì; bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí ó sì ṣe ìrìbọmi ni nwọ́n jẹ́ ti ìjọ Ọlọ́run; nítorí ìdí ìgbàgbọ́ nwọn nínú ọ̀rọ̀ Álmà. Ó sì ṣe, tí ọba Mòsíà fún Álmà ní ẹ̀tọ́ l á t i dá àwọn ìjọ-Ọlọ́run sílẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; ó sì fún un ní àṣẹ kí ó yan àwọn àlùfã, àti olùkọ́ni lórí ìjọ-Ọlọ́run kọ̣́kan. Nísisìyí, a ṣe eleyĩ nítorípé àwọn ènìyàn pọ̀ púpọ̀ tí a kò lè ṣe àkóso fún nípasẹ̀ olùkọ́ni kanṣoṣo; bẹ̃ sì ni nwọ́n kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú àpéjọ kanṣoṣo; Nítorínã, nwọ́n kó ara nwọn jọ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, tí à npè ní ìjọ; ìjọ kọ̣́kan sì ní àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni tirẹ̀, àlùfã kọ̣́kan sì nwãsù ọ̀rọ̀ nã gẹ́gẹ́bí a ṣe fi lée lọ́wọ́ láti ẹnu Álmà. Àti bayi, l’áìṣírò àwọn ìjọ pọ̀ púpọ̀, gbogbo nwọn jẹ́ ìjọ kanṣoṣo, bẹ̃ni, àní ìjọ-Ọlọ́run; nítorítí kò sí ohun kan tí a wãsù nínú gbogbo ìjọ wọ̀nyí bíkòṣe ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Àti nísisìyí ìjọ méje ni ó wà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Ó sì ṣe pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá ní ìfẹ́ láti gba orúkọ Krístì, tàbí ti Ọlọ́run, ni nwọ́n darapọ̀ mọ́ àwọn ìjọ-Ọlọ́run. A sì pè nwọ́n ní ènìyàn Ọlọ́run. Olúwa sì da Ẹ̀mí i rẹ̀ lé nwọn lórí, nwọ́n sì di alábùkún-fún, nwọ́n sì ṣe rere lórí ilẹ̀ nã. 26 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Ìjọ nã ni a darí sínú ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ àwọn aláìgbàgbọ́—Álmà gba ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun—Àwọn tí ó ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀, tí a sì rìbọmi gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀–Àwọn ọmọ ìjọ nínú ẹ̀ṣẹ̀, tí nwọ́n bá ronúpìwàdà tí nwọ́n sì jẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀ fún Álmà àti fún Olúwa ni a o dáríjì; bíkòṣe bẹ̃, a kì yíò kà nwọ́n mọ́ àwọn ènìyàn Ìjọ nã. Ní ìwọ̀n ọdún 120– 100 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí, ó sì ṣe tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìran tí ó ndìde kò lè ní òye àwọn ọ̀rọ̀ ọba Bẹ́njámínì, nítorítí nwọ́n wà ní kékeré nígbàtí ó bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀; nwọn kò sì gba àṣà àwọn bàbá nwọn gbọ́. Nwọn kò sì gba ohun tí a sọ nípa àjĩnde òkú gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò sì gbàgbọ́ nípa bíbọ̀ Krístì. Àti nísisìyí, nítorí àìgbàgbọ́ nwọn, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò yé nwọn; ọkàn nwọn sì sé le. Nwọn kò sì ṣe ìrìbọmi, bẹ̃ni nwọn kò darapọ̀ mọ́ ìjọ. Nwọ́n sì jẹ́ ènìyàn ìyàsọ́tọ̀ nítorí ìgbàgbọ́ ọ nwọn, nwọ́n sì rí báyĩtítí, àní nínú ipò àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ nwọn; nítorítí nwọn kò ní ké pe Olúwa Ọlọ́run nwọn. Àti nísisìyí, ní àkokò ìjọba Mòsíà, nwọ́n kò pọ̀ tó ìdajì àwọn ènìyàn Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nítorí ìyàpa lãrín àwọn arákùnrin wọn, nwọn pọ̀ síi. Nítorí ó ṣe, tí nwọ́n tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, àwọn tí nwọ́n wà nínú ìjọ, tí nwọ́n sì mú nwọn dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀púpọ̀; nítorínã ó di ohun tí ó tọ́ pé kí àwọn tí nwọ́n ti dẹ́ṣẹ̀, tí nwọ́n sì wà nínú ìjọ, gba ìbáwí láti ọwọ́ ìjọ. Ó sì ṣe tí a mú nwọn wá síwájú àwọn àlùfã, tí àwọn olùk ọ́ n i s ì f i nwọ́n l é ọwọ́ àwọn àlùfã; àwọn àlùfã sì mú nwọn wá síwájú Álmà, ẹnití íṣe olórí àlùfã. Nísisìyí, ọba Mòsíà ti fún Álmà ní àṣẹ lórí ìjọ-Ọlọ́run. Ó s ì ṣe t í Álmà kò mọ́ ohunkóhun nípa nwọn; ṣùgbọ́n àwọn ẹlẹ́rĩ wá sí nwọn; bẹ̃ni, àwọn ènìyàn nã dúró nwọ́n sì jẹ̃rí sí gbogbo àìṣedẽdé nwọn lọ́pọ̀lọpọ̀. Nísisìyí, kò sí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyĩ tí ó ṣẹlẹ̀ rí nínú ìjọ; nítorínã, ọkàn Álmà dàrú nínú rẹ̀, ó sì ní kí nwọ́n mú nwọn wá síwájú ọba. Ó sì wí fún ọba pé: Kíyèsĩ, àwọn wọ̀nyí ni àwa mú wá síwájú rẹ, tí àwọn arákùnrin nwọn ti fẹ̀sùnkàn nwọ́n; bẹ̃ni, nwọ́n sì t i mú nwọn nínú onírurú ìwà àìṣedẽdé. Nwọn kò sì ronúpìwàdà àìṣedẽdé nwọn; nítorínã ni àwa ṣe mú nwọn tọ̀ ọ́ wá, kí ìwọ kí ó lè ṣe ìdájọ́ nwọn gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ nwọn. Ṣùgbọ́n ọba Mòsíà wí fún Álmà pé: Kíyèsĩ, èmi kò ní ṣe ìdájọ́ nwọn; nítorínã, èmi fi nwọ́n lé ọ lọ́wọ́ fún ìdájọ́. Àti nísisìyí ọkàn Álmà tún dàrú nínú rẹ̀; ó sì lọ bẽrè lọ́wọ́ Olúwa nípa ohun tí òun yíò ṣe nípa ọ̀rọ̀ yí, nítorítí ó bẹ̀rù fún ṣíṣe ohun tí ó kùnà níwájú Olúwa. Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí ó ti tú gbogbo ọkàn rẹ̀ jáde sí Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ọ́ wá, wípé: Alábùkún-fún ni ìwọ, Álmà, alábùkún-fún sì ni àwọn tí a rìbọmi nínú omi Mọ́mọ́nì. Ìwọ jẹ́ alábùkún-fún nítorí títóbi ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ mi Ábínádì nìkanṣoṣo. Alábùkún-fún sì ni nwọ́n nítorí títóbi ìgbàgbọ́ nwọn nínú ọ̀rọ̀ èyítí ìwọ ti sọ fún nwọn nìkanṣoṣo. Alábùkún-fún sì ni ìwọ nítorí ìwọ ti ṣe ìdásílẹ̀ ìjọ-Ọlọ́run lãrín àwọn ènìyàn yí; a ó sì fi ìdí nwọn múlẹ̀, nwọn yíò sì jẹ́ ènìyàn mi. Bẹ̃ni, alábùkún-fún ni àwọn ènìyàn yí tí nwọ́n ní ìfẹ́ sí jíjẹ́ orúkọ mi; nítorítí nínú orúkọ mi ni a o pè nwọ́n; tèmi sì ni nwọ́n íṣe. Àti nítorípé ìwọ ti wádĩ lọ́wọ́ mi nípa olùrékọjá nnì, alábùkún-fún ni ìwọ. Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ íṣe; èmi sì bá ọ dá májẹ̀mú wípé ìwọ yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun; ìwọ yíò sì sìn mí, ìwọ yíò sì jáde lọ ní orúkọ mi, ìwọ yíò sì gbá àwọn àgùtàn mi jọ. Ẹnití ó bá gbọ́ ohùn mi ni yíò jẹ́ àgùtàn mi; òun ni ìwọ yíò sì gbà sínú ìjọ nã, òun nã ni èmi yíò sì gbà. Nítorí kíyèsĩ, èyí ni ìjọ mi; ẹníkẹ́ni tí a bá ti rìbọmi ni a ó rìbọmi sí ìrònúpìwàdà. Ẹnìkẹ́ni tí ẹ̀yin bá sì gbà ni yíò gba orúkọ mi gbọ́; òun sì ní èmi yíò dáríjì ní ọ̀fẹ́. Nítorípé èmi ni ẹni nã tí ó gbé ẹ̀ṣẹ̀ ayé rù ara mi; nítorípé èmi ni ẹni nã tí ó dá nwọn; èmi sì ni ẹni nã tí ó fifún ẹnití ó bá gbàgbọ́ dé òpin, ãyè ní apá ọ̀tún mi. Nítorí kíyèsĩ, ní orúkọ mi ni a pè nwọ́n; tí nwọ́n bá sì mọ̀ mí, nwọn yíò jáde wá, nwọn yíò sì ní ãyè ayérayé ní apá ọ̀tún mi. Yíò sì ṣe nígbàtí ìpè ìkejì yíò dún nígbànã ni àwọn tí nwọn kò mọ̀ mí rí yíò jáde wá, tí nwọn yíò sì dúró níwájú mi. Nígbànã ni nwọn yíò sì mọ̀ wípé èmi ni Olúwa Ọlọ́run nwọn, pé èmi ni Olùràpadà nwọn; ṣùgbọ́n a kì yíò rà nwọ́n padà. Nígbànã ni èmi yíò sì jẹ́wọ́ fún nwọn pé èmi kò mọ̀ nwọ́n rí; nwọn yíò sì kọjá sínú iná àìnípẹ̀kun èyítí a pèsè sílẹ̀ fún èṣù àti àwọn ángẹ́lì rẹ̀. Nítorínã, mo wí fún yín, wípé ẹnití kò bá gbọ́ ohùn mi, òun ni ẹ̀yin kì yíò gbà sínú ìjọ mi, òun sì ni èmi kì yíò gbà ní ọjọ́ ìkẹhìn. Nítorínã mo wí fún ọ, Lọ; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì ré mi kọjá, òun ni ìwọ́ yíò ṣe ìdájọ́ fún gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ tí òun ti ṣẹ̀; tí ó bá sì jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ níwájú rẹ àti èmi, tí ó sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ tọkàn-tọkàn, òun ni ìwọ yíò dáríjì, èmi yíò sì dáríjĩ pẹ̀lú. Bẹ̃ni, ní gbogbo ìgbà tí àwọn ènìyàn mi bá ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ní èmi yíò dárí gbogbo ìrékọjá nwọn sí mi jì nwọ́n. Ẹ̀yin nã pẹ̀lú yíò dárí àwọn ìrékọjá ji ara yín; nítorí lọ́ótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnití kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ọmọnìkejì rẹ̀ nígbàtí ó bá sọ wípé òun ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀, olúwarẹ̀ ti mú ara rẹ̀ wá sí ìdálẹ́bi. Nísisìyí, mo wí fún ọ, Lọ; ẹnìkẹ́ni ti kò bá sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, òun kannã ni a kì yíò kà mọ́ àwọn ènìyàn mi; èyí ni a ó sì kíyèsí láti ìsisìyí lọ. Ó sì ṣe, nígbàtí Álmà ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó kọ nwọ́n sílẹ̀, kí òun lè ní nwọn, àti pẹ̀lú kí ó lè ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ìjọ nã gẹ́gẹ́bí òfin Ọlọ́run. Ó sì ṣe tí Álmà lọ tí ó sì ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ti mú nínú àìṣedẽdé, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Oluwa. Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó sì jẹ́wọ́ nwọn, àwọn ni ó kà mọ́ àwọn ènìyàn ìjọ nã; Àwọn tí nwọn kò bá sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nwọn kí nwọ́n sì ronúpìwàdà àìṣedẽdé nwọn, àwọn kannã ni a kò kà mọ́ àwọn ènìyàn ìjọ nã, a sì pa orúkọ nwọn rẹ́. Ó sì ṣe tí Álmà to gbogbo ìṣe ìjọ lẹ́sẹ̃sẹ; nwọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀sí ní àlãfíà, nwọ́n sì nṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ìṣe ìjọ nã, nwọ́n nrìn pẹ̀lú ìkíyèsára níwájú Ọlọ́run, nwọ́n ngba ọ̀pọ̀lọpọ̀, nwọ́n sì ri ọ̀pọ̀lọpọ̀ bọmi. Àti nísisìyí, gbogbo ohun wọ̀nyí ni Álmà pẹ̀lú àwọn olùjọṣiṣẹ́ rẹ̀ ṣe, tí nwọ́n wà lórí ìjọ nã, tí nwọn nrìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́, tí nwọn nkọ́ni lọ́rọ̀ Ọlọ́run nínú ohun gbogbo, tí nwọn nfaradaonírurú ìpọ́njú, tí àwọn tí nwọn kì íṣe ara ìjọ Ọlọ́run nṣe inúnibíni sí nwọn. Nwọ́n sì bá àwọn arákùnrin nwọn wí; gbogbo nwọn sì gba ìbáwí, olúkúlùkù nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tàbí bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ èyítí òun ṣẹ̀, tí Ọlọ́run sì ti pã láṣẹ fún nwọn kí nwọ́n gbàdúrà láìsinmi, kí nwọn sì máa dúpẹ́ nínú ohun gbogbo. 27 Mòsíà fi òfin de inúnibíni òun sì pàṣẹ fún ìbamu lọ́gbọ̣́gba—Álmà kékeré pẹ̀lú mẹ́rin nínú àwọn ọmọ Mòsíà lépa láti pa ìjọ nã run—Ángẹ́lì kan farahàn nwọ́n ó sì pa á láṣẹ kí nwọ́n dẹ́kun ibi ṣíṣe—Álmà ya odi—Gbogbo ènìyàn ni ó níláti di àtúnbí láti gba ìgbàlà—Álmà pẹ̀lú àwọn ọmọ Mòsíà nkede ìhìn ayọ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 100 sí 92 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí inúnibíni tí àwọn aláìgbàgbọ́ gbé ti ìjọ pọ̀ púpọ̀ tó bẹ̃ tí ìjọ bẹ̀rẹ̀sí kùn, tí nwọ́n sì nráhùn sí àwọn olórí nwọn nípa ọ̀rọ̀ nã; nwọ́n sì fi ọ̀rọ̀ nã sun Álmà. Álmà sì gbé ọ̀rọ̀ nã síwájú ọba nwọn, Mòsíà. Mòsíà sì fi ọ̀rọ̀ nã lọ àwọn àlùfã rẹ̀. Ó sì ṣe tí Mòsíà ọba fi ìkéde ránṣẹ́ jákè-jádò ilẹ̀ nã pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀, pé aláìgbàgbọ́ kankan kò gbọ́dọ̀ ṣe inúnibíni sí ẹnìkẹ́ni tí ó wà nínú ìjọ Ọlọ́run. Àṣẹ tí ó múná sì wà jákè-jádò àwọn ìjọ pé kí inúnibíni kí ó máṣe wà lãrín nwọn, àti pé kí ìbámu lọ́gbọ̣́gba wà lãrín gbogbo ènìyàn; Pé kí nwọ́n máṣe j ẹ́ kí ìgbéraga tàbí ìrera dí àlãfíà a nwọn lọ́wọ́; pé kí olúkúlùkù ka ọmọnìkejì rẹ̀ sí ara rẹ̀, kí nwọ́n sì máa ṣe iṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ ara nwọn fún ìpèsèfún ara nwọn. Bẹ̃ni, kí gbogbo àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ nwọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ nwọn fún ìpèsè fún ara nwọn, ní gbogbo ìgbà àfi nínú àìlera, tàbí nínú àìní; lẹ́hìn tí wọ́n sì ti ṣe ohun wọ̀nyí, nwọn pọ̀ púpọ̀ nínú ọ́re-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Àláfíà púpọ̀ sì bẹ̀rẹ̀sí padà sórí ilẹ̀ nã; àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí pọ̀ púpọ̀, nwọ́n sì ngbilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, bẹ̃ni, ní àríwá àti ní gúsù, ní ìlà-oòrùn, àti ní ìwọ̀-oòrùn, nwọ́n sì nkọ́ àwọn ìlú nlá-nlá pẹ̀lú ìletò ní gbogbo ẹ̀kún ìlú nã. Olúwa sì bẹ̀ nwọ́n wò, ó sì ṣe rere fún nwọn, nwọ́n sì di ọ̀pọ̀ àti ọlọ́rọ̀ ènìyàn. Nísisìyí, a ka àwọn ọmọkùnrin Mòsíà mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́; àti pẹ̀lú, a ka ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Álmà mọ́ nwọn, ẹnití à npe orúkọ rẹ̀ ní Álmà èyí tí íṣe ti bàbá rẹ̀, bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó ya ènìyàn búburú àti abọ̀rìṣà. Ẹnú rẹ̀ si dùn, ó sì nsọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn púpọ̀púpọ̀ fún àwọn ènìyàn; nítorínã ó darí ọpọlọpọ ninu àwọn ènìyàn nã lati ṣe àìṣedẽdé bí tirẹ̀. Ó sì jẹ́ ìfàsẹ́hìn nlá sí ìlọsíwájú ìjọ Ọlọ́run; tí ó sì darí ọkàn àwọn ènìyàn lọ; tí ó sì jẹ́ kí ìyapa nlá wà lãrín àwọn ènìyàn nã; tí ãyè sì ṣí sílẹ̀ fún ọ̀tá Ọlọ́run láti lo agbára rẹ̀ lórí nwọn. Àti nísisìyí, ó sì ṣe, nígbàtí ó nlọ kãkiri fún ìparun ìjọ Ọlọ́run, nítorítí ó nlọ kãkiri ní ìkọ̀kọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Mòsíà, tí o sì nwá láti pa ìjọ nã run, àti fúnìṣìlọ́nà àwọn ènìyàn Olúwa, ní ìlòdì sí àṣẹ́ Ọlọ́run, tàbí ti ọba pãpã— Gẹ́gẹ́bí èmi sì ti wí fún nyín, bí nwọ́n ṣe nlọ kãkiri tí nwọ́n nṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, kíyèsĩ, ángẹ́lì Olúwa yọ sí nwọn; ó sì sọ̀kalẹ̀ bí ẹnipé ó wà nínú àwọ̀-sánmà; ó sì sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́bí ohùn àrá tí ó nsán, tí ó mú kí ilẹ̀ tí nwọ́n dúró le mi títí; Ẹnu si yà nwọ́n púpọ̀púpọ̀, tí nwọ́n ṣubú lulẹ̀, ọ̀rọ̀ tí ó nbá nwọn sọ kò sì yé nwọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó tún kígbe, ó ní: Álmà; dìde, kí ó sì bọ́ síwájú, nítorí ìdí wo ni ìwọ fi nṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run? Nítorítí Ọlọ́run ti sọ wípé: Èyí yĩ ni ìjọ mi, èmi yíò sì dã sílẹ̀; kò sì sí ohun tí yíò bĩ ṣubú, bíkòbájẹ́ ìwà ìrékọjá àwọn ènìyàn mi. Àti pẹ̀lú, ángẹ́lì nã sọ wípé: Kíyèsĩ, Olúwa ti gbọ́ àdúrà àwọn ènìyàn rẹ̀, àti àdúrà ìránṣẹ́ rẹ̀, Álmà, ẹnití ìṣe bàbá rẹ; nítorítí ó ti gbàdúrà pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàgbọ́ nípa rẹ, pé kí a lè mu ọ wá sínú ìmọ̀ òtítọ́ nnì; nítorínã, nítorí ìdí èyí ni èmi wá láti lè fún ọ ní ìdánilójú nípa agbára àti àṣẹ Ọlọ́run, kí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lè jẹ́ gbígbà gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ nwọn. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, njẹ́ ìwọ lè jiyàn agbára Ọlọ́run? Nìtorí kíyèsĩ, njẹ́ ohùn mi kò mi ayé? Njẹ́ ìwọ kò tilẹ̀ rí mi níwájú rẹ̀? A sì rán mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nísisìyí mo wí fún ọ: Lọ, kí ó sì rántí ìgbèkun àwọn bàbá rẹ̀ ní ilẹ̀ Hẹ́lámì; àti ní ilẹ̀ Nífáì; kí ó sì rántí àwọn ohun nlá tí ó ti ṣe fún nwọn; nítorítí nwọ́n wà nínú oko-ẹrú, ó sì kó nwọn yọ. Àti nísisìyí, èmi wí fún ọ, Álmà, máa bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, kí ó sì dẹ́kun lílépa ìparun ìjọ nã, kí àdúrà nwọn lè gbà bí ìwọ yíò bá tilẹ̀ pa ara rẹ̀ run. Àti nísisìyí, ó sì ṣe pé àwọn ohun wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ìkẹhìn tí ángẹ́lì nã sọ fún Álmà, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ. Àti nísisìyí, Álmà pẹ̀lú àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tún ṣubú lulẹ̀, nítorí títóbi ni ìyanu nwọn; nítorípé, pẹ̀lú ojú ara nwọn ni nwọ́n rí ángẹ́lì Olúwa; ohùn rẹ̀ sì dàbí àrá, èyítí ó mi ilẹ̀; nwọ́n sì mọ̀ wípé kò sí ohun míràn bíkòṣe agbára Ọlọ́run tí ó lè mi ilẹ̀ tí yíò sì gbọ̀n tìtì bí èyítí yíò là sí méjì. Àti nísisìyí ìyàlẹ́nu Álmà pọ̀ tóbẹ̃ gẹ̃ tí ó fi yadi, tí kò sì lè la ẹnu rẹ̀; bẹ̃ni, ó sì di aláìlágbára tó bẹ̃ tí kò lè gbé ọwọ́ rẹ̀; nítorínã àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ gbé e, nwọ́n sì gbé e láì le ran ara rẹ lọ́wọ́, àní títí nwọ́n fi tẹ́ ẹ sí iwájú bàbá rẹ̀. Nwọ́n sì sọ gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí nwọn fún bàbá rẹ̀; bàbá rẹ̀ sì yọ̀, nítorí ó mọ̀ wípé agbára Ọlọ́run ni. Ó sì mú kí àwọn ènìyàn péjọ, kí nwọ́n lè jẹ́ ẹ̀rí sí ohun tí Olúwa ti ṣe fún ọmọ rẹ̀, àti pẹ̀lú fún àwọn tí nwọn wà pẹ̀lú rẹ̀. Ó sì mú kí àwọn àlùfã péjọ pọ̀; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gba ãwẹ̀, àti gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run nwọn, pé kí ó la ẹnu Álmà, kí ó lè sọ̀rọ̀, àti kí ẹ̀yà ara rẹ̀ lè gba okun—kí ojú àwọn ènìyàn lè là, kí nwọ́n lè ri àti kí nwọ́n sì mọ̀ nípa dídára àti ògo Ọlọ́run. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí nwọ́n ti gba ãwẹ̀, tí nwọ́n sì ti gbàdúrà fún ìwọ̀n ọjọ́ méjì àti òru méjì,ẹ̀yà-ara Álmà gba okun padà, ó sì dìde dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀sí ọ̀rọ̀ sísọ sí nwọn, pé kí nwọ́n tújúká: Nítorítí, ó wípé, mo ti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi, a sì ti rà mí padà nípa ti Olúwa; ẹ kíyèsĩ, a ti bí mi nípa ti Ẹ̀mí. Olúwa sì wí fún mi pé: Máṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu pé gbogbo ènìyàn, bẹ̃ni, ọkùnrin àti obìnrin, gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè àti ènìyàn, níláti di àtúnbí; bẹ̃ni, kí a bí nwọn nípa ti Ọlọ́run, kí a yí nwọn padà kúrò ní ipò ara àti ìsubu tí nwọ́n wà, sí ipò ìwà-òdodo, nítorítí a ti rà nwọ́n padà nípa ti Ọlọ́run, tí nwọ́n sì di ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin; Báyĩ sì ni nwọ́n di ẹ̀dá titun; láì sì ṣe èyí, kò sí ọ̀nà tí nwọn yíò fi jogún ìjọba Ọlọ́run. Mo wí fún nyín, bí kò bá rí báyĩ, a o gbé nwọn sọnù; mo sì mọ́ èyí, nítorípé díẹ̀ ni ó kù kí a gbé mi sọnù. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, lẹ́hìn tí èmi ti la ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú kọjá, tí èmi sì ronúpìwàdà dé ẹnu ikú, Olúwa nínú ãnú ríi pé ó tọ́ kí òun kí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ jíjóná ayérayé, a sì bí mi nípa ti Ọlọ́run. A ti ra ẹ̀mí mi padà kúrò lọ́wọ́ òrọ́ró ìkorò, àti ìdè àìṣedẽdé. Mo wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ èyítí ó ṣókùnkùn jùlọ; ṣùgbọ́n nísisìyí, mo rí ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run èyítí ó yani lẹ́nu. Oró ayérayé gba ọkàn mi; ṣùgbọ́n a já mi gbà, kò sì sí ìrora fún ọkàn mi mọ́. Mo kọ Olùràpadà mi, mo sì sẹ́ èyí tí àwọn bàbá wa ti sọ nípa rẹ̀; ṣùgbọ́n nísisìyí, kí nwọn lè ríi pé ó nbọ̀wá, àti pé ó ṣe ìrántí gbogbo ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀, òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí ènìyàn gbogbo. Bẹ̃ni, gbogbo ẽkún yíò wólẹ̀, gbogbo ahọ́n ni yíò sì jẹ́wọ́ níwájú rẹ̀. Bẹ̃ni, àní ní ọjọ́ ìkẹhìn, nígbàtí gbogbo ènìyàn yíò dúró kí òun lè ṣe ìdájọ́ nwọn, nígbànã ni nwọn yíò jẹ́wọ́ pé òun ni Ọlọ́run; nígbànã ni nwọn yíò jẹ́wọ́, àwọn tí nwọn ngbé ilé ayé ní àìní Ọlọ́run, pé ìdájọ́ ìyà títí ayé lórí nwọn jẹ́ èyítí ó tọ́; nwọn yíò sì gbọ̀n, nwọn yíò sì wárìrì, nwọn yíò sì súnrakì lábẹ́ ìwo ojú rẹ̀ tí ó nwò ohun gbogbo. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Álmà bẹ̀rẹ̀ láti àkokò yí lọ láti máa ṣe ìkọ́ni àwọn ènìyàn nã, àwọn tí nwọ́n sì wà pẹ̀lú Álmà nígbàtí ángẹ́lì farahàn nwọ́n, tí nwọ́n sì nṣe ìrìnàjò kãkiri nínú gbogbo ilẹ̀ nã, tí nwọ́n nkéde fún gbogbo àwọn ènìyàn nã, àwọn ohun tí nwọ́n ti gbọ́ àti èyí tí nwọ́n rí, tí nwọ́n sì nwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú, nítorítí àwọn aláìgbàgbọ́ nṣe inúnibíni sí nwọn lọ́pọ̀lọpọ̀, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nwọn sì nkọlù nwọ́n. Ṣùgbọ́n láì ka gbogbo ohun wọ̀nyí sí, nwọ́n tu àwọn ènìyàn ìjọ-Ọlọ́run nínú púpọ̀púpọ̀, nwọ́n sì ntì nwọ́n lẹ́hìn nínú ìgbàgbọ́ nwọn, tí nwọ́n sì ngbà nwọ́n níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra, àti ọ̀pọ̀ lãlã láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Mẹ́rin nínú nwọn ni ísì ṣe àwọn ọmọ Mòsíà; orúkọ nwọn sì ni Ámọ́nì, àti Áárọ́nì, Òmnérì, àti Hímnì; èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Mòsíà. Nwọ́n sì rin ìrìnàjò jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti lãrín àwọn ènìyàn tí nwọ́n wà lábẹ́ìjọba ọba Mòsíà, tí nwọ́n sì nfi tọkàn-tara lépa láti ṣe àtúnṣe àwọn ohun búburú tí nwọ́n ti ṣe sí ìjọ, tí nwọ́n sì njẹ́wọ́ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, tí nwọ́n nkéde gbogbo ohun tí nwọ́n ti rí, tí nwọ́n sì nṣe àlàyé àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìwé-mímọ́ sí gbogbo ẹnití ó fẹ́ láti gbọ́ nwọn. Báyĩ ni nwọ́n sì ṣe jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, fún mímú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí ìmọ̀ òtítọ́, bẹ̃ni, sí ìmọ̀ Olùràpadà nwọn. Báwo sì ni nwọ́n ṣe jẹ́ alábùkún- fún tó! Nítorítí nwọn kéde àlãfíà; nwọ́n sì kéde ìhìnrere ohun rere; nwọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn nã pé Olúwa jọba. 28 Àwọn ọmọkùnrin Mòsíà lọ láti wãsù sí àwọn ará Lámánì—Nípa lílo àwọn òkúta aríran nnì, Mòsíà ṣe ìyípadà àwọn àwo Járẹ́dì. Ní ìwọ̀n ọdún 92 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn tí àwọn ọmọ Mòsíà ti ṣe gbogbo nkan wọ̀nyí, nwọ́n mú àwọn díẹ̀ pẹ̀lú nwọn, nwọ́n sì padà sí ọ̀dọ̀ bàbá nwọn, ọba, nwọ́n sì rọ̀ ọ́ pé kí ó gbà fún nwọn kí nwọ́n kọjá lọ sí ilẹ̀ ti Nífáì pẹ̀lú àwọn tí nwọn ti yàn, kí nwọn lè wãsù àwọn ohun tí nwọ́n ti gbọ́, kí nwọ́n sì lè kọ́ àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì, ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run— Pé, bóyá, nwọ́n lè mú nwọn wá sí ìmọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn, kí nwọ́n sì jẹ́ kí nwọ́n mọ̀ dájú nípa àìṣedẽdé àwọn bàbá nwọn; àti pé, bóyá, nwọn yíò gbà nwọ́n kúrò nínú ikorira wọn sí àwọn ará Nífáì, pé kí a lè mú àwọn nã wá sí ipò ayọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run nwọn, pé kí nwọ́n lè mú ara nwọn lọ́rẹ́, àti kí ìjà kí ó dẹ́kun ní gbogbo ilẹ̀ nã èyítí Olúwa Ọlọ́run nwọn ti fún nwọn. Nísisìyí, nwọ́n fẹ́ kí a kéde ìgbàlà sí gbogbo ẹ̀dá, nítorítí nwọn kò lè gbà pé kí ẹ̀mí ènìyàn kan kí ó parun; bẹ̃ni, àní pé ẹ̀mí kan lè faradà oró àìnípẹ̀kun mú kí nwọ́n gbọ̀n, kí nwọ́n sì wá rìrì. Báyĩ sì ni Ẹ̀mí Olúwa ṣiṣẹ́ lórí nwọn, nítorítí nwọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó burú jùlọ. Olúwa sì rí i pé ó tọ́ nínú ãnú rẹ̀ tí kò lópin pé kí a dá nwọn sí; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n ṣe àròkàn ọkàn nítorí àìṣedẽdé nwọn, tí nwọn njìyà púpọ̀, tí nwọ́n sì nbẹ̀rù pé a ó ta nwọ́n nù, títí láé. Ó sì ṣe tí nwọ́n ṣípẹ̀ fún bàbá nwọn fún ọjọ́ púpọ̀ pé kí nwọ́n lọ sí ilẹ̀ ti Nífáì. Ọba Mòsíà sì lọ bẽrè lọ́wọ́ Olúwa bí òun bá lè jẹ́ kí àwọn ọmọ òun lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Lámánì kí nwọ́n lè wãsù ọ̀rọ̀ nã. Olúwa sì wí fún Mòsíà pé: Jẹ́ kí nwọ́n kọjá lọ nítorípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yíò gba ọ̀rọ̀ nwọn gbọ́, nwọn ó sì ní ìyè àìnípẹ̀kun; èmi yíò sì yọ àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí Mòsíà jẹ́ kí nwọ́n lọ, kí wọ́n sì ṣe bí nwọ́n ti bẽrè. Nwọ́n sì mú ìrìnàjò nwọn pọ̀n kọjálọ sínú aginjù, láti lọ wãsù ọ̀rọ̀ nã lãrín àwọn ọmọ Lámánì; èmi yíò sì sọ nípa ìṣe nwọn lẹ́hìn èyí. Nísisìyí ọba Mòsíà kò rí ẹnití yíò gbé ìjọba lé lórí, nítoríkò sí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó fẹ́ gba ìjọba nã. Nítorínã, ó gbé ìwé ìrántí nã èyítí a fin sí órí àwọn àwo idẹ, pẹ̀lú àwọn àwo ti Nífáì, àti gbogbo ohun tí ó fi pamọ́ gẹ́gẹ́bí àṣẹ Ọlọ́run, lẹ́hìn tí ó ti ṣe ìyírọ̀-padà, tí ó sì jẹ́ kí a kọ àwọn ìwé ìrántí èyítí ó wà lórí àwọn-àwo wúrà, èyítí àwọn ará Límháì wá rí, èyítí a gbé lé e lọ́wọ́ nípasẹ̀ ọwọ́ Límháì; Èyí ni ó sì ṣe nítorí àníyàn àwọn ènìyàn rẹ̀; nítorítí nwọ́n ní ìfẹ́ èyítí ó rékọjá láti mọ̀ nípa àwọn ènìyàn nã tí a ti parun. Àti nísisìyí ni ó sì ṣe yíyí ọ̀rọ̀ nã padà sí èdè míràn nípa àwọn òkúta méjì nnì tí a wé mọ́ etí méjẽjì ọpọn kan. Nísisìyí àwọn ohun wọ̀nyí ni a ti pèsè sílẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, tí a sì gbé lélẹ̀ láti ìran dé ìran, fún ìtumọ̀ èdè gbogbo; A sì ti pa nwọ́nmọ́ nípa ọwọ́ Olúwa, pé kí ó lè fi han gbogbo ẹ̀dá tí yíò jogún ilẹ̀ nã, gbogbo àìṣedẽdé àti ìwà ìríra àwọn ènìyàn rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ní àwọn ohun wọ̀nyí ni á npè ní aríran gẹ́gẹ́bí ti ìgbà àtijọ́. Nísisìyí, lẹ́hìn tí Mòsíà ti parí yíyí ọ̀rọ̀ àwọn ìwé ìrántí wọ̀nyí padà sí èdè míràn, kíyèsĩ, ó sọ nípa àwọn ènìyàn nã tí a parun, láti ìgbà tí nwọ́n ti pawọ́n run títí padà sí ìgbà kíkọ́ ilé ìṣọ́ gíga nnì, ní àkokò tí Olúwa da èdè àwọn ènìyàn nã rú, tí a sì tú nwọn ká lórí ilẹ̀ ayé gbogbo, bẹ̃ni, àní láti àtẹ̀hìnwá, títí lọ sí ìgbà dídá Ádámù. Nísisìyí ọ̀rọ̀ yí jẹ́ kí àwọn ènìyàn Mòsíà ṣọ̀fọ̀ gidigidi, bẹ̃ni, nwọ́n kún fún ìrora-ọkàn; bíótilẹ̀ríbẹ̃ ó fún nwọn ní ìmọ̀ púpọ̀, nínú èyí tí nwọ́n yọ̀. Ọ̀rọ̀ yí ni a ó sì kọ lẹ́hìn èyí; nítorí kíyèsĩ, ó jẹ́ ohun tí ó yẹ pe kí gbogbo ènìyàn mọ àwọn ohun tí a kọ sínú àkọsílẹ̀ yí. Àti nísisìyí, gẹ́gẹ́bí mo ti wí fún yín lẹ́hìn tí ọba Mòsíà ti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí, ó mú àwọn àwo idẹ nã, àti gbogbo àwọn ohun tí ó kó pamọ́, ó sì gbé nwọn lé ọwọ́ Álmà, ẹnití íṣe ọmọ Álmà; bẹ̃ni, gbogbo ìwé ìrántí, pẹ̀lú àwọn olùtumọ̀-èdè, ó sì gbé nwọn lé e lọ́wọ́, ó sì pàṣẹ pé kí ó pa nwọ́n mọ́, kí ó sì ṣe ìwé ìrántí àwọn ènìyàn nã, kí ó sì gbé nwọn lé ọwọ́ ìran kan dé òmíràn, àní gẹ́gẹ́bí a ṣe gbé nwọn lé ọwọ́ àwọn ènìyàn láti ìgbà ti Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù. 29 Mòsíà dá ìmọ̀ràn kí a yan àwọn adájọ́ dípò ọba—Àwọn ọba aláìṣòdodo a máa kó àwọn ènìyàn nwọn sínú ẹ̀ṣẹ̀—A yan Álmà kékeré ní onídàjọ́ gíga nípa ohùn àwọn ènìyàn—Ó sì tún íṣe olórí àlùfã lórí Ìjọ—Álmà àgbà àti Mòsíà kú. Ní ìwọ̀n ọdún 92 sí 91 kí a tobí Olúwa wa. Nísisìyí, nígbàtí Mòsíà ti ṣe èyí, ó ránṣẹ́ jákè-jádò ilẹ̀ nã, lãrín àwọn ènìyàn, o fẹ láti mọ́ ìfẹ́ nwọn nípa ẹni tí yíò ṣe ọba nwọn. Ó sì ṣe tí ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn dé, wípé: Àwa ní ìfẹ́ kí Áárọ́nì ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọba àti olórí wa. Nísisìyí, Áárọ́nì ti kọjá lọ sí ilẹ̀ Nífáì, nítorínã ọba kò lè gbé ìjọba lée lọ́wọ́; bẹ̃ sì ni Áárọ́nì kò ní gba ìjọba nã; bẹ̃ sì ni kò sí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Mòsíà tí ó ní ìfẹ́ láti gba ìjọba nã. Nítorínã, ọba Mòsíà tún ránṣẹ́ lãrín àwọn ènìyàn nã; bẹ̃ni, àní ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ nã sí àwọn ènìyàn nã. Èyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kọ wípé: Kíyèsĩ, A! ẹ̀yin ènìyàn mi, tàbí arákùnrin mi, nítorítí mo kà yín kún bẹ̃, èmi ní ìfẹ́ kí ẹ tún ọ̀rọ̀ nã rò, èyítí a pè yín kí ẹ rò—nítorítí ẹ ní ìfẹ́ láti ní ọba. Nísisìyí, mo wí fún yín pé ẹnití ìjọba tọ́ sí ti kọ̣́, kò sì ní gba ìjọba nã. Àti nísisìyí, tí a bá sì yan ẹlòmíràn rọ́pò rẹ̀, kíyèsĩ, èmi bẹ̀rù pé ìjà yíò bẹ́ sílẹ̀ lãrín yín. Tani ó sì mọ̀ bóyá ọmọ mi, ẹnití ìjọba nã jẹ́ tirẹ̀ yíò bínú, tí yíò sì kó apá kan nínú àwọn ènìyàn yí lọ tẹ̀lée, èyítí yíò dá ogun àti ìjà sílẹ̀ lãrín yín, èyítí yíò sì fa ìtàjẹ̀sílẹ̀, àti yíyí ọ̀nà Olúwa padà, bẹ̃ni, tí nwọ́n yíò sì pa ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn run. Nísisìyí mo wí fún yín, ẹ jẹ́ kí a gbọ́n kí a sì ro àwọn ohun wọ̀nyí, nítorí a kò ní ẹ̀tọ́ láti pa ọmọ mi run, bẹ̃ sì ni a kò gbọ́dọ̀ ní ẹ̀tọ́ láti pa ẹlòmíràn tí a bá yàn dípò o rẹ̀ run. Bí ọmọ mi bá sì padà sí ipò agbéraga àti ohun asán, òun yíò sẹ́ ìrántí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ, yíò sì gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ sí ìjọba, èyítí yíò mú kí òun àti àwọn ènìyàn yí dá ẹ̀ṣẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Àti nísisìyí, ẹ jẹ́ kí a jẹ́ ọlọgbọ́n, kí a sì fi ọkàn sí ohun wọ̀nyí, kí àwa kí ó sì ṣe èyítí yíò mú àlãfíà wà lãrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Nítorínã, èmi yíò jẹ́ ọba yín fún ìyókù ọjọ́ ayé mi; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ẹ jẹ́ kí a yan àwọn onídàjọ́, kí nwọ́n máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí òfin wa; àwa yíò sì ṣe ìlànà titun fún àkóso àwọn ènìyàn yí nítorítí àwa yíò yan àwọn ọlọ́gbọ́n ènìàn gẹ́gẹ́bí onídàjọ́, tí nwọn yíò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn yí gẹ́gẹ́bí àwọn òfin Ọlọ́run. Nísisìyí, ó sàn kí a ṣe ìdájọ́ ènìyàn nípa Ọlọ́run ju nípa ènìyàn, nítorítí awọn ìdájọ́ Ọlọ́run jẹ́ èyítí ó tọ́ nígbà-gbogbo, ṣùgbọ́n awọn ìdájọ́ ènìyàn jẹ́ èyítí kò tọ́ nígbà-gbogbo. Nítorínã, tí ó bá ṣẽṣe kí ẹ̀yin kí ó ní àwọn ènìyàn tí ó tọ́ láti jẹ́ àwọn ọba yín, tí nwọ́n yíò fi awọn òfin Ọlọ́run múlẹ̀, tí nwọn yíò sì ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn yí gẹ́gẹ́bí àwọn òfin rẹ̀, bẹ̃ni, bí ẹ̀yin bá lè ní àwọn ènìyàn láti jẹ́ àwọn ọba yín tí nwọn yíò ṣe àní gẹ́gẹ́bí bàbá mi Bẹ́njámínì ti ṣe fún àwọn ènìyàn yĩ—mo wí fún yín, bí ó bá lè rí báyĩ nígbà-gbogbo, nígbànã ni yíò tọ́ kí ẹ̀yin ní ọba nígbà-gbogbo láti jọba lórí yín. Èmi pãpã ti tiraka pẹ̀lú gbogbo agbára àti ipá tí mo ní, láti kọ́ yín ní àwọn òfin Ọlọ́run, àti láti fi àlãfíà lélẹ̀ jákè-jádò ilẹ̀ nã, pé kí ogun tàbí ìjà má wà, kí ó má ṣe sí olè jíjà tàbí ìkógun, tàbí ìpànìyàn tàbí ìwà àìṣedẽdé, bí ó tilè wù kí ó rí; Ẹnìkẹ́ni tí o bá sì ti hu ìwà àìṣedẽdé, òun ni èmi ti jẹ níyàgẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, gẹ́gẹ́bí òfin tí àwọn bàbá wa ti fún wa. Nísisìyí, mo wí fún yín pé nítorítí gbogbo ènìyàn jẹ́ aláìṣọ́tọ́, kò tọ́ kí ẹ ní ọba tàbí àwọn ọba kí nwọ́n jọba lórí i yín. Nítorí kíyèsĩ, báwo ni ìwà àìṣedẽdé ọba búburú yíò ti tó, bẹ̃ni, báwo ni ìparun nã yíò ti tóbi tó! Bẹ̃ni, ẹ ṣe ìrántí ọba Nóà, ìwà búburú àti ìwà ìríra rẹ̀, àti ìwà búburú àti ìwà ìríra àwọn ènìyàn rẹ̀. Ẹ kíyèsĩ ìparun nlá tí ó wá sórí nwọn; àti pẹ̀lú, nítorí àìṣedẽdé nwọn, nwọn bọ́ sínú oko-ẹrú. Bí kò bá sì ṣe nítorí àkóyọ Ẹlẹ́dã nwọn ẹnití ó gbọ́n jùlọ, àti pẹ̀lú ìrònúpìwàdà àtọkànwá nwọn, nwọn yíò wà nínú okoẹrú dandan títí àkokò yí. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ó gbà nwọ́n nítorípé nwọ́n rẹ ara nwọn sílẹ̀ níwájú rẹ̀; àti nítorípé nwọ́n kígbe pè é lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú; báyĩ sì ni Olúwa nṣiṣẹ́ nínú agbára rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, lãrín àwọn ọmọ ènìyàn, tí ó sì nna ọwọ́ ãnú rẹ̀ sí àwọn tí nwọ́n bá gbẹ́kẹ̀lé e. Kíyèsĩ, nísisìyí mo wí fún yín, ẹ̀yin kò lè lé ọba aláìṣedẽdé kúrò lórí ìtẹ́ àfi nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjà pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀. Nítorí kíyèsĩ ó ni àwọn ọ̀rẹ́ nínú àìṣedẽdé, òun sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ara rẹ̀; òun sì yí òfin àwọn tí ó jọba nínú òtítọ́ ṣãjú rẹ̀ padà; ó sì ntẹ àwọn òfin Ọlọ́run mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀; Ó sì fi awọn òfin lélẹ̀, ó sì fi nwọ́n ránṣẹ́ sí ãrin àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̃ni, awọn òfin ní ìbámu pẹ̀lú ìwà-búburú rẹ̀; ẹnìkẹ́ni tí kò bá sì pa awọn òfin rẹ̀ wọ̀nyí mọ́, ni ó mú kí nwọ́n parun; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì ta kò ó, òun yíò rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti kọlũ ú ní ogun, tí ó bá sì lè ṣeé, yíò pa nwọ́n run; báyĩ sì ni ọba búburú nnì yíò ṣe yí ọ̀títọ́ gbogbo ọ̀nà òdodo padà. Àti nísisìyí kíyèsĩ, mo wí fún yín, kò tọ̀nà pé kí irú awọn ìwà ìríra báyĩ kí ó wá sí órí yín. Nítorínã, ẹ yan àwọn onídàjọ́ nípa ohùn àwọn ènìyàn wọ̀nyí, kí nwọ́n lè ṣe ìdájọ́ yín gẹ́gẹ́bí òfin èyítí a ti fún nyín nípasẹ̀ àwọn bàbá wa, èyítí ó pé, èyítí a sì ti fún nwọn nípa ọwọ́ Olúwa. Nísisìyí, kò wọ́pọ̀ kí ohùn àwọn ènìyàn lè ní ìfẹ́ sí ohun tí ó lòdì sí èyítí ó tọ́; ṣùgbọ́n ó wọ́pọ̀ kí díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ní ìfẹ́ sí ohun tí kò tọ́; nítorínã, èyí yíi ni ẹ̀yin yíò gbà, tí ẹ̀yin yíò sì mú u ṣe òfin yín—kí ẹ̀yin kí ó ṣe àkóso ara yín nípa ohùn àwọn ènìyàn yín. Tí àkokò nã bá sì dé tí ohùn àwọn ènìyàn bá yan àìṣedẽdé, nígbànã ní àkokò tí ìdájọ́ Ọlọ́run yíò wá sórí yín; bẹ̃ni, nígbànã ni òun yíò bẹ̀ yín wò pẹ̀lú ìparun nlá, àní bí ó ti bẹ ilẹ̀ yí wò ní ìgbà kan rí. Àti nísisìyí bí ẹ̀yin bá ní àwọn adájọ́, tí nwọn kò sì ṣe ìdájọ́ yín gẹ́gẹ́bí òfin, èyítí a ti fún yín, ẹ̀yin lè ní kí adájọ́ tí ó ga jù ú ṣe ìdájọ́ rẹ̀. Bí àwọn adájọ́ gíga yín kò bá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́, ẹ̀yin yíò mú kí díẹ̀ nínú àwọn adájọ́ kékeré yín kójọ pọ̀, nwọn yíò sì ṣe ìdájọ́ àwọn adájọ́ gíga yín, gẹ́gẹ́bí ohùn àwọn ènìyàn. Mo sì pàṣẹ fún yín kí ẹ ṣe ohun wọ̀nyí nínú ìbẹ̀rù Olúwa; mo sí pàṣẹ fún yín kí ẹ ṣe àwọn ohun wọ̀nyí, pé kí ẹ̀yin máṣe ní ọba; pé bí àwọn ènìyàn yí bá dá ẹ́ṣẹ̀ àti tí nwọ́n ṣe àìṣedẽdé a ó sì bẹ̀ nwọ́n wò lórí ará nwọn. Nítorí kíyèsĩ mo wí fún yín, ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní ó jẹ́ wípé ìwà àìṣedẽdé awọn ọba nwọn ni ó fã; nítorínã, a o sì bẹ ìwà àìṣedẽdé nwọn wò lórí àwọn ọba nwọn. Àti nísisìyí, mo ní ìfẹ́ kí àìdọ́gba yĩ dópin lórí ilẹ̀ yí, pãpã lãrín àwọn ènìyàn mi yí; ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ilẹ̀ yí jẹ́ ilẹ̀ òmìnira, olúkúlùkù yíò sì ní ẹ̀tọ́ àti ànfàní bákannã, títí dé ìgbàtí Olúwa yíò kã sí ọgbọ́n pé kí àwa kí ó yè kí a sì jogún ilẹ̀ nã, bẹ̃ni, àní títí dé ìgbà tí àwọn ìran wa yíò fi wà lórí ilẹ̀ nã. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun míràn ni ọba Mòsíà sì kọ sí nwọn, tí ó nfi hàn nwọ́n nípa gbogbo àdánwò àti lãlã ọba olódodo, bẹ̃ni, gbogbo lãlã ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àti gbogbo ìráhùn àwọn ènìyàn sí ọba nwọn; ó sì fi gbogbo rẹ̀ yé nwọn. Ó sì wí fún nwọn pé àwọn ohun wọ̀nyí kò yẹ kí ó rí bẹ̃; ṣùgbọ́n pé ẹrù yí yẹ kí ó jẹ́ ti gbogbo ènìyàn, kí olúkúlùkù lè faradà èyítí ó tọ́ sí i. Ó sì tún sọ fún wọn nípa ìpalára èyítí yíò jẹ́ tiwọn, nípa níní ọba búburú lórí nwọn; Bẹ̃ni, gbogbo àìṣedẽdé àti ìwà ìríra rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ogun, àti ìjà, àti ìtàjẹ̀sílẹ̀, àti olè jíjà, àti ìkógun, àti ìwà àgbèrè, àti onírurú ìwà àìṣedẽdé èyítí a kò lè sọ—tí ó sì nsọ fún wọn pé kò yẹ kí àwọn ohun wọ̀nyí rí bẹ̃, pé nwọ́n lòdì pátápátá sí awọn òfin Ọlọ́run. Àti nísisìyí ó sì ṣe, lẹ́hìn tí ọba Mòsíà ti ránṣẹ́ báyĩ sí àwọn ènìyàn nã, nwọ́n gbà pé ọ̀títọ́ ni awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorínã, nwọn kọ ìfẹ́ láti ní ọba sílẹ̀, nwọ́n sì ṣe àníyàn lọ́pọ̀lọpọ̀ pé kí olúkúlùkù ní ànfàní ọgbọ̣́gba jákè-jádò ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, olúkúlùkù sì sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ láti dáhùn sí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀. Nítorínã, ó sì ṣe tí nwọ́n kó ara nwọn jọ nísọrí-ìsọrí jákè-jádò ilẹ̀ nã, kí nwọ́n sọ nípa tani yíò ṣe olùdájọ́ nwọn, láti ṣe ìdájọ́ nwọn gẹ́gẹ́bí òfin tí a ti fún nwọn; nwọ́n sì yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí òmìnira èyítí a ti fún nwọn. Nwọ́n sì tẹ̀ síwájú lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ìfẹ́ sí Mòsíà; bẹ̃ni, nwọ́n kà á kún kọjá ẹlòmíràn; nítorítí nwọn kò kà á sí aninilára, tí ó nwá ìfà fún ara rẹ̀, bẹ̃ni, fún ìfẹ́ owó, èyítí ó ndíbàjẹ́ ẹ̀mí; nítorítí kò gba ọrọ̀ lọ́wọ́ nwọn, kò sì ní inúdídùn sí ìtàjẹ̀sílẹ̀; ṣùgbọ́n ó ti fi àlãfíà lélẹ̀ lórí ilẹ̀ nã, ó sì ti gbà fún àwọn ènìyàn nã pé kí nwọ́n bọ́ lọ́wọ́ onírurú oko-ẹrú; nítorínã ni nwọ́n ṣe buyì fún, bẹ̃ni, lọ́pọ̀lọpọ̀ kọjá ìwọ̀n. Ó sì ṣe, tí nwọ́n yan àwọn onídàjọ́ láti ṣe àkóso lórí nwọn, tàbí láti ṣe ìdájọ́ nwọn gẹ́gẹ́bí òfin; èyí ni nwọ́n sì ṣe jákè-jádò ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí a yan Álmà gẹ́gẹ́bí onídàjọ́ àgbà àkọ́kọ́, tí òun sì tún jẹ́ olórí àlùfã, nítorítí bàbá rẹ̀ ti gbé ìpè nã lé e lọ́wọ́, tí ó sì ti fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ètò ìjọ-Ọlọ́run. Ati nísisìyí ó sì ṣe, tí Álmà nrìn ní ọ̀nà Olúwa, ó sì pa àwọnòfin rẹ̀ mọ́, ó sì ṣe ìdájọ́ òdodo; àlãfíà sì wà títí lórí ilẹ̀ nã. Báyĩ sì ni ìjọba àwọn onídàjọ́ bẹ̀rẹ̀ jákè-jádò ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, lãrín gbogbo àwọn ènìyàn tí à npè ní ará Nífáì; Álmà sì ni onídàjọ́ àgbà àkọ́kọ́. Àti nísisìyí ni ó sì ṣe tí bàbá rẹ̀ kú, ní ọmọ ọgọ́rin àti ọdún méjì, lẹ́hìn tí ó ti gbé ìgbé ayé ní pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Ó sì ṣe tí Mòsíà nã kú, nínú ọgbọ̀n ọdún àti ìkẹ́ta ti ìjọba rẹ̀, tí ó sì jẹ́ ọmọ ọgọ́ta ọdún àti mẹ́ta; gbogbo rẹ̀ ní àpapọ̀ sì jẹ́ ọgọ́rún mãrún àti mẹ́sán ọdún láti ìgbà tí Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Báyĩ sì ni ìjọba àwọn ọba lórí àwọn ènìyàn Nífáì dé òpin; báyĩ sì ni ọjọ́ ayé Álmà dé òpin, ẹnití ó jẹ́ olùdásílẹ̀ ìjọ nwọn. 1 Néhórì nkọ́ni lẹ́kọ̣́ èké, ó dá ìjọ kan sílẹ̀, ó sì mú iṣẹ́ àlùfã àrékérekè wá, ó sì pa Gídéónì—A pa Néhórì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—Àwọn iṣẹ́ àlùfã àrékérekè pẹ̀lú inúnibíni tàn lãrín àwọn ènìyàn nã—Àwọn àlùfã pèsè fún àìní ara nwọn, àwọn ènìyàn nã nṣe ìtọ́jú àwọn tálákà, Ìjọ-Ọlọ́run nã sí ṣe rere. Ní ìwọ̀n ọdún 91 sí 88 kí a tó bí Olúwa wa. NÍSISÌYÍ ó sì ṣe, ní ọdún kíni tí ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, láti ìsisìyí lọ, tí Mòsíà ọba, lẹ́hìntí ó ti re ibi gbogbo ayé írè, tí ó sì ti ja ogun rere, tí ó sì ti rìn ní ìdúróṣinṣin níwájú Ọlọ́run, tí kò sì fi ẹnìkẹ́ni sílẹ̀ pé kí ó jọba dípò ara rẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó ti fi àwọn òfin lélẹ̀, àwọn ènìyàn sì ti gbà wọ́n; nítorínã nwọn níláti pa àwọn òfin nã mọ́, èyítí ó ti ṣe. Ó sì ṣe pé ní ọdún kíni ìjọba Álmà lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ọkùnrin kan wà tí a mú wá síwájú rẹ̀ pé kí a dájọ́ fún un, ẹnití ó tóbi tí a sì mọ̀ ọ́ fún agbára rẹ̀. Òun sì ti lọ lãrín àwọn ènìyàn nã, tí ó sì nwãsù sí nwọn èyítí òun pè ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì nṣe àtakò ìjọ-Ọlọ́run tí ó nsọ fún àwọn ènìyàn nã pé gbogbo àlùfã àti olùkọ́ni yẹ kí nwọ́n jẹ́ olókìkí; àti pé kò yẹ kí nwọ́n fi ọwọ́ nwọn ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n pé àwọn ènìyàn nwọn níláti ṣe àtìlẹhìn nwọn. Òun sì ṣe ìjẹ́rĩ pẹ̀lú sí àwọn ènìyàn nã pé gbogbo ènìyàn ni a ó gbà là ní ọjọ́ ìkẹhìn, àti pé kí nwọn kí ó máṣe bẹ̀rù tàbí wárìrì, ṣùgbọ́n pé kí nwọ́n gbé orí nwọn sókè, kí nwọ́n sì yọ̀; nítorítí Olúwa ti dá gbogbo ènìyàn, ó sì ti ra gbogbo ènìyàn padà; àti pé, ní ìkẹhìn, gbogbo ènìyàn yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ó sì ṣe tí ó nkọ́ni ní àwọn ohun wọ̀nyí tó bẹ̃gẹ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gba àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, àní púpọ̀ tó bẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀ sĩ ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un, tí nwọ́n sì nfún un ní owó. Ó sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìgbéraga nínú ìgbéraga ọkàn rẹ̀, tí ó sì nwọ àwọn aṣọ olówó-iyebíye, bẹ̃ni, ó sì bẹ̀rẹ̀sí dá ìjọ sílẹ̀ pẹ̀lú, gẹ́gẹ́bí ìlànà ìwãsù rẹ̀. Ó sì ṣe bí ó ti nlọ, láti wãsù sí àwọn tí ó gba ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ gbọ́, ó bá ọkùnrin kan pàdé, ẹnití íṣe ti ìjọ-Ọlọ́run, bẹ̃ni, àní ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ni nwọn; òun sì bẹ̀rẹ̀sĩ jiyàn pẹ̀lú rẹ̀ kíkan-kíkan, pé kí òun lè darí àwọn ènìyàn ìjọ nã kúrò; ṣùgbọ́n ọkùnrin nã kọjú ìjà síi, ó sì rọ̀ ọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nísisìyí orúkọ ọkùnrin nã ni Gídéónì; òun sì ni ẹni tí ó jẹ́ ohun èlò lọ́wọ́ Ọlọ́run láti gba àwọn ènìyàn Límháì kúrò nínú oko-ẹrú. Nísisìyí, nítorípé Gídéónì kọjú ìjà síi pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó bínú sí Gídéónì ó sì fa idà rẹ̀ yọ, ó sì bẹ̀rẹ̀sí ṣáa. Gẹ́gẹ́bí Gídéónì ti pọ̀ ní ọjọ́, nítorínã, òun kò lè dojú kọ lílù u rẹ̀, nítorínã, a fi idà pa á. Ẹni nã tí ó pa á ni àwọn ènìyàn ìjọ-Ọlọ́run mú wá sí iwájú Álmà, kí a lè dájọ́ fún un gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀. Ó sì ṣe tí òun wá síwájú Álmà, tí ó sì wí àwíjàre fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgboyà. Ṣùgbọ́n Álmà wí fún un pé: wọ́, èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a ó ri iṣẹ́ àlùfã àrékérekè lãrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Sì kíyèsĩ, ìwọ kò jẹ̀bi iṣẹ́ àrékérekè nìkan, ṣùgbọ́n ìwọ ti gbìyànjú láti ṣe bẹ̃ pẹ̀lú idà; tí o bá sì ri bẹ̃ pé a ó fi ipá ṣe iṣẹ́ àlùfã àrékérekè lãrín àwọn ènìyàn yíi yíò já sí ìparun nwọn pátápátá. Ìwọ sì ti ta ẹ̀jẹ̀ olódodo sílẹ̀, bẹ̃ni, ẹni tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun dáradára lãrín àwọn ènìyàn yíi; tí àwa bá sì dá ọ sí, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yíò wá sórí wa fún ẹ̀san. Nítorínã, a dá ọ lẹ́bi lati ikú, gẹ́gẹ́bí òfin èyítí Mòsíà, ọba wa ti ó jẹ kẹ́hìn ti fi fún wa; àwọn ènìyàn yĩ sì ti gbã, nítorínã, àwọn ènìyàn yíi níláti tẹ̀lé òfin. Ó sì ṣe tí nwọ́n múu; orúkọ rẹ̀ sì ni Néhórì; nwọ́n sì gbé e lọ sórí òkè Mántì, níbẹ̀ ni a sì ṣe ti, tàbí ni ó sì gba, ní ãrin àwọn ọ̀run òun ayé, wípé ohun èyítí òun ti kọ́ àwọn ènìyàn lòdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; níbẹ̀ ni ó sì kú ikú ìtìjú. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, èyí kò fi òpin sí ìtànkalẹ̀ iṣẹ́ àlùfã àrékérekè jákè-jádò ilẹ̀ nã; nítorítí àwọn tí nwọ́n ní ìfẹ́ sí àwọn ohun asán ayé pọ̀, nwọ́n sì nlọ láti wãsù àwọn ẹ̀kọ́ èké; èyí ni nwọ́n sì ṣe nítorí ọrọ̀ àti ọlá. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n kò jẹ́ purọ́, nítorípé tí a bá mọ́ irọ́ nwọn, nítorí ìbẹ̀rù òfin, nítorípé a máa jẹ àwọn òpùrọ́ níyà, nítorínã nwọ́n wãsù bí ẹnipé bí ìgbàgbọ́ nwọnṣe rí ni èyí; àti nísisìyí, òfin kò lè de ẹnikẹ́ni fún ìgbàgbọ́ rẹ̀. Nwọn kò sì jalè, fún ìbẹ̀rù òfin, nítorítí wọn a máa fi ìyà jẹ irú àwọn bẹ̃; bẹ̃ ni nwọn kò gbọ́dọ̀ fi ipá jalè, tàbí ṣe ìpànìyàn, nítorítí ẹnití ó bá pànìyàn ni a ó fi ìyà jẹ de oju ikú. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe, tí àwọn tí nwọn kĩ ṣe ará ìjọ-Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀sĩ ṣe inúnibíni sí àwọn tĩ ṣe ará ìjọ-Ọlọ́run, tí nwọ́n sì ti gba orúkọ Krístì lé ara nwọn. Bẹ̃ni, nwọ́n nṣe inúnibíni sí nwọn, nwọ́n sì nyọ nwọ́n lẹ́nu pẹ̀lú onírurú ọ̀rọ̀, èyĩ nítorí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ nwọn; nítorítí nwọn kò gbéraga lójú ara nwọn, àti nítorítí nwọn sọ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ní ọ̀kan pẹ̀lú òmíràn, láìgbowó àti láìdíyèlé. Nísisìyí, òfin tí ó múná kan wà lãrín àwọn ènìyàn ìjọ nã, pé kí ẹnìkẹ́ni tĩ bá íṣe ti ìjọ-Ọlọ́run, máṣe ṣe inúnibíni sí àwọn tí kĩ ṣe ti ìjọ-Ọlọ́run, àti pé kí inúnibíni má sì ṣe wà lãrín ara nwọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà nínú nwọn tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìgbéraga, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣe àríyànjiyàn líle pẹ̀lú àwọn tí ó lòdì sí nwọn, tí nwọ́n fi nlu ara nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n lu ara pẹ̀lú ìkũkù. Èyí sì jẹ́ ọdún kejì ìjọba Álmà, ó sì jẹ́ ohun tí ó mú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú bá ìjọ; bẹ̃ni, ó jẹ́ ohun tí ó mú ọ̀pọ̀ ìdánwò fún ìjọ nã. Nítorítí a mú ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sé le, a sì ti pa orúkọ nwọn rẹ́, tí a kò sì rántí nwọn mọ́ lãrín àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Àti bákannã, ọ̀pọ̀lọpọ̀ yọ ara nwọn kúrò lãrín nwọn. Nísisìyí, eleyĩ jẹ́ ìdánwò nlá fún àwọn tí nwọ́n dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n dúró ṣinṣin láìyẹsẹ̀ ní pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ nwọ́n sì faradà gbogbo inúnibíni tí a fi bẹ̀ nwọ́n wò pẹ̀lú ìrọ́jú. Nígbàtí àwọn àlùfã sì fi iṣẹ́ nwọn sílẹ̀ láti kọ́ àwọn ènìyàn nã ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn ènìyàn nã bákannã fi iṣẹ́ nwọn sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbàtí àlùfã bá sì ti kọ́ nwọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tán gbogbo nwọn a tún padà sí ṣíṣe iṣẹ́ nwọn tọkàntara; àlùfã nã kò sì ka ara rẹ̀ kún níwájú àwọn olùgbọ́ rẹ̀, nítorítí oníwãsù kò sunwọ̀n ju olùgbọ́ lọ, olùkọ́ni nã pẹ̀lú kò sunwọ̀n ju akẹ́kọ̣́ lọ; bẹ̃ni gbogbo nwọn jẹ́ ọgbọ̣́gba, nwọ́n sì jọ nṣe iṣẹ́ olúkúlùkù, gẹ́gẹ́bí agbára rẹ̀. Nwọ́n sì nṣe ìfifún ni nínú ohun ìní nwọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí èyí tí ó ní, fún àwọn tálákà, àwọn aláìní, àwọn aláìsàn, àti àwọn tí ìyà njẹ; nwọn kò sì wọ aṣọ olówo-iyebíye, síbẹ̀ nwọ́n fínjú, nwọ́n sì lẹ́wà. Báyĩ ni nwọ́n sì ṣe fi ojúṣe ìjọ-Ọlọ́run nã lélẹ̀; báyĩ sì ni nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ní àlãfíà tí ó pẹ́ títí, l’áìṣírò nwọn nṣe inúnibíni sí nwọn. Àti nísisìyí, nítorí ìdúróṣinṣin ìjọ nã, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ní ọrọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nwọ́n ní ọ̀pọ̀ ohun gbogbo tí nwọ́n ṣe aláìní—ọ̀pọ̀ agbo-ẹran àti ọ̀wọ́-ẹran, àti àwọn onírũrú àbọ́pa, àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èso, àti wúrà, àti fàdákà, àti àwọn ohun oníyebíye, àti ọ̀pọ̀ aṣọ ṣẹ̀dá àti aṣọ ọ̀gbọ tí ó jọjú, àti onírũrú aṣọ ìwọ́lẹ̀. Bẹ̃ gẹ́gẹ́, nínú ipò ãsìkí yíi, nwọn kò ta ẹnikẹ́ni ti o wà ni ìhòhònù, tàbí tí ebi npa, tàbí tíòngbẹ ngbẹ, tàbí tí ó ṣàìsàn, tàbí tí kò rí jẹ tó; nwọn kò sì kó ọkàn nwọn lé ọrọ̀; nítorínã, nwọ́n lawọ́ sí gbogbo ènìyàn; àgbà àti ọmọdé, pẹ̀lú ẹnití ó wà ní ìdè tàbí ní òmìnira, ọkùnrin àti obìnrin, yálà ní òde ìjọ Ọlọ́run tàbí ní inú ìjọ-Ọlọ́run, tí nwọn kò sì ṣe ojúṣãjú ènìyàn ní ti ẹni tí ó ṣe aláìní. Ati bẹ̃ gẹ́gẹ́ ní nwọ́n ní ãsìkí, tí nwọ́n sì ní ọrọ̀ ju àwọn tí nwọn kò jẹ́ ti ìjọ nã lọ. Nítorítí àwọn tí nwọn kĩ ṣe ará ìjọ nã ti kún fún ìwà àrékérekè, àti ìbọ̀rìṣà, àti nínú ọ̀rọ̀ asán tàbí ìmẹ́lẹ́, à t i ì l a r a àti asọ̀; tí nwọ́n nwọ aṣọ olówóiyebíye; tí nwọ́n nrú ọkàn nwọn sókè nínú ìgbéraga ojú ti ara nwọn; ìṣe inúnibíni, irọ́ pípa, olè jíjà, fífi ipá jalè, ṣíṣe àgbèrè àti ìpànìyàn, àti onírũrú ìwà búburú; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a fi òfin de gbogbo àwọn tí nwọn bá rée kọjá, níwọ̀n bí a ti lè ṣeé. Ó sì ṣe, nígbàtí a sì fi òfin lélẹ̀ báyĩ fún nwọn, tí olúkúlùkù sì jìyà gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, nwọ́n sì pọ̀ síi, nwọn kò sì hu ìwà búburú èyí tí a lè mọ̀; nítorínã àlãfíà púpọ̀ wà lãrín àwọn ènìyàn Nífáì títí dé ọdún karũn ìjọba àwọn ónídàjọ̣́. 2 Ámlísì wá ọ̀nà láti jẹ ọba, a sì kọ̀ọ́ nípa ohùn àwọn ènìyàn—Àwọn ọmọ-ẹ̀hin rẹ̀ fi jọba—Àwọn ará Ámlísì bá àwọn ará Nífáì jà, a sì ṣẹ́gun nwọn—Àwọn ará Lámánì pẹ̀lú àwọn ará Ámlísì dára pọ̀ a sì ṣẹ́gun nwọn—Álmà pa Ámlísì. Ní ìwọ̀n ọdún 87 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún karũn ìjọba nwọn tí ìjà bẹ̀rẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn nã; nítorítí ọkùnrin kan tí à npè ní Ámlísì, tí òun sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n-àrekérekè ènìyàn, bẹ̃ni, ọlọ́gbọ́n ènìyàn gẹ́gẹ́bí ogbọ́n ayé, tí òun sì jẹ́ ẹ̀yà ti ọkùnrin nì èyítí ó pa Gídéónì pẹ̀lú idà, ẹnití a pa gẹ́gẹ́bí òfin— Nísisìyí Ámlísì yí, nípa ọgbọ́n-àrekérekè rẹ̀, ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sọ́dọ̀ rẹ̀; àní tóbẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ní agbára; tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gbìyànjú láti fi Ámlísì jọba lórí àwọn ènìyàn nã. Nísisìyí, èyí jẹ́ ìdágìrì fún àwọn ènìyàn ìjọ-Ọlọ́run, àti fún gbogbo àwọn tí nwọ́n tẹ̀lé ẹ̀tàn Ámlísì; nítorítí nwọ́n mọ̀ pé gẹ́gẹ́bí òfin nwọn, irú ohun báyĩ níláti jẹ́ ṣíṣe nípa ohùn àwọn ènìyàn nã. Nítorínã, tí ó bá ṣeéṣe kí Ámlísì rí àtìlẹhìn àwọn ènìyàn nã nípa ohùn nwọn, gẹ́gẹ́bí ó ti jẹ́ ènìyàn búburú, òun yíò fi ẹ̀tọ́ àti ànfàní nwọn nínú ìjọ-Ọlọ́run dù nwọ́n; nítorítí ó jẹ́ ète rẹ̀ láti pa ìjọ-Ọlọ́run run. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã kó ara nwọn jọ papọ̀ jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí èrò ọkàn rẹ̀, yálà fún ìfaramọ́ tàbí atakò Ámlísì, ní àjọ ọ̀tọ̀tọ̀, tí nwọ́n sì ní àríyànjiyàn àti asọ̀ tí ó yanilẹ́nu ní ãrin ara nwọn. Báyĩ sì ni nwọ́n péjọ̀ láti di ìbò nípa ọ̀rọ̀ nã; a sì gbée síwájú àwọn onídàjọ́. Ó sì ṣe, tí ohùn àwọn ènìyàn tako Ámlísì, tí a kò sì fi ṣe ọba lórí àwọn ènìyàn nã. Nísisìyí, eleyĩ mú kí àwọn tí ó tako ó láyọ̀ púpọ̀ lọ́kàn nwọn; ṣùgbọ́n Ámlísì rú àwọn tí ó fẹ́ẹ sókè sí ìrunú àwọn tí kò fẹ́ ẹ. Ó sì ṣe tí nwọn kó ara nwọn jọ, tí nwọ́n sì ya Ámlísì sọ́tọ̀ láti jẹ ọba nwọn. Nísisìyí nígbàtí a fi Ámlísì jọba lórí nwọn, ó pàṣẹ pé kí nwọ́n dìhámọ́ra ogun ní ìdojúkọ àwọn arákùnrin wọn; èyí ni ó sì ṣe láti tẹ̀ wọ́n lori bá lábẹ́ ara rẹ̀. Nísisìyí àwọn ènìyàn Ámlísì jẹ́ ìyàtọ̀ nípa orúkọ Ámlísì, a sì npè nwọ́n ní àwọn ará Ámlísì; àwọn tí ó kù ni a sì npè ní àwọn ará Nífáì, tàbí àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Nítorínã àwọn ará Nífáì ní ìmọ̀ ète àwọn ará Ámlísì, nítorínã nwọ́n gbáradì sílẹ̀ láti dojúkọ nwọ́n; bẹ̃ni, nwọ́n gbáradì pẹ̀lú idà, àti pẹ̀lú dòjé-ìjà, àti pẹ̀lú ọrún, àti pẹ̀lú ọ̀kọ̀, àti pẹ̀lú òkúta, àti pẹ̀lú kànnàkànnà, àti pẹ̀lú onírũrú ohun ìjà ogun gbogbo. Báyĩ sì ni nwọ́n ṣe gbáradì láti dojúkọ àwọn ará Ámlísì ní àkokò tí nwọn bá dé. Nwọ́n sì yan àwọn balógun, àti àwọn balógun gíga, àti àwọn balógun agba, gẹ́gẹ́bí pípọ̀sí àwọn ọmọ ogun nwọn. Ó sì ṣe tí Ámlísì ṣe ìgbáradì fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú onírũrú ohun ìjà ogun gbogbo; ó sì yan olórí àti olùdarí lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí, láti darí nwọn lọ sógun ní ìdojúkọ àwọn arákùnrin nwọn. Ó sì ṣe tí àwọn ará Ámlísì wá sí orí òkè Ámníhù, èyítí ó wà ní ìhà ìlà ọ́rùn odò Sídónì, tí ó ṣàn létí ilẹ̀ ti Sarahẹ́múlà, níbẹ̀ ni nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí jagun pẹ̀lú àwọn ará Nífáì. Nísisìyí, Álmà, nítorítí ó jẹ́ onídàjọ́ agba, àti gómìnà àwọn ènìyàn Nífáì, nítorínã ó kọjá lọ sókè pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̃ni, pẹ̀lú àwọn balógun rẹ̀, àti àwọn balógun àgbà, bẹ̃ni, ní ipò olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ní ìdojúkọ àwọn ará Ámlísì lógun. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa àwọn ará Ámlísì lórí òkè nã ní ìhà apá ilà-oòrùn Sídónì. Àwọn ará Ámlísì sì dojúkọ àwọn ará Nífáì pẹ̀lú ọ̀pọ̀ agbára, tó bẹ̃ tí púpọ̀ nínú àwọn ará Nífáì ṣubú níwájú àwọn ará Ámlísì. Bíótilẹ̀ríbẹ̃ Olúwa fún àwọn ará Nífáì ní agbára, tí nwọ́n sì pa àwọn ará Ámlísì ní ìpakúpa, tí nwọ́n sì nsálọ kúrò níwájú nwọn. Ó sì ṣe, tí àwọn ará Nífáì súré lé àwọn ará Ámlísì ní gbogbo ọjọ́ nã, nwọ́n sì pa nwọ́n ní ìpakúpa, tó bẹ̃ tí a fi pa àwọn ẹgbẹ̀rún méjìlá àti ọgọ̣́rún mãrún àti ọgbọ̀n àti méjì lára àwọn ará Ámlísì; à sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ̣́rún mãrún àti ọgọ̣́ta àti méjì lára àwọn ará Nífáì. Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ọmọ ogun Álmà kò lè sáré lé àwọn ará Ámlísì mọ́, ó pàṣẹ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ pàgọ́ nwọ́n sì àfonífojì Gídéónì, àfonífojì èyítí a fi orúkọ Gídéónì nnì sọ, ẹnití Néhórì pa pẹ̀lú idà; nínú àfonífojì yíi sì ni àwọn ará Nífáì pàgọ́ nwọn sí ní alẹ́ ọjọ́ nã. Álmà sí rán àwọn amí tẹ̀lé àwọn ìyókù àwọn ará Ámlísì, kí òun kí ó lè mọ́ èrò nwọn pẹ̀lú rìkíṣí nwọn, kí ó lè ṣe ìdãbò bò ara rẹ̀, kí òun lè pa àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìparun. Nísisìyí, àwọn tí ó rán jáde láti ṣọ́ ibùdó àwọn ará Ámlísì ni a pè ní Sérámù, àti Ámnórì, àti Mántì, àti Límhérì; àwọn wọ̀nyí ni ó jáde lọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn, láti ṣọ́ ibùdó àwọn ará Ámlísì. Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kejì tí nwọ́n sì padà sí ibùdó àwọn ará Nífáì ní ìkánjú, nítorítí ẹnu yà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi, nwọ́n wípé: Kíyèsĩ, àwa tẹ̀lé àgọ́ ará Ámlísì, ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wa pé ní ilẹ̀ Mínọ́nì, ní apá òkè ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ní ọ̀nà tí ó lọ sí ilẹ̀ Nífáì, àwa rí ọ̀pọ̀ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì; sì wọ́, àwọn ará Ámlísì ti darapọ̀ mọ́ nwọn; Nwọ́n sì ti kọlũ àwọn arákùnrin wa ní ilẹ̀ nã; nwọ́n sì nsá kúrò níwájú nwọn pẹ̀lú àwọn agbo-ẹran nwọn, àti àwọn aya nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn, síhà ìlú-nlá wa; àti pé tí àwa kò bá ṣe kánkán nwọn yíò gba ìlú-nlá wa, àti àwọn bàbá wa, àti àwọn aya wa, àti àwọn ọmọ wa ní nwọn yíò pa. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn Nífáì kó àgọ́ nwọn, tí nwọ́n sì jáde kúrò nínú àfonífojì Gídéónì, sí ìhà ìlú-nlá nwọn, èyítí íṣe ìlú-nlá Sarahẹ́múlà. Sì kíyèsĩ, bí nwọ́n ṣe ndá odò Sídónì kọjá ni àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Ámlísì, tí nwọ́n pọ̀ bĩ yanrìn òkun, kọlũ nwọ́n láti pa nwọ́n run. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, gẹ́gẹ́bí a ti fi agbára fún àwọn ará Nífáì láti ọwọ́ Olúwa, nígbàtí nwọ́n ti gbàdúrà tagbára-tagbára síi kí ó lè gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, nítorínã Olúwa sì gbọ́ igbe nwọn, ó sì fún nwọn ní ágbára, àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Ámlísì sì ṣubú níwájú nwọn. Ó sì ṣe tí Álmà bá Ámlísì ja pẹ̀lú idà, tí nwọ́n dojúkọ ara nwọn; nwọ́n sì jà kíkan-kíkan, ọ̀kan pẹ̀lú ìkejì. Ó sì ṣe, tí Álmà ẹnití íṣe ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ó sì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàgbọ́, kígbe, wípé: A! Olúwa, ṣãnú, kí o s‘idá ẹ̀mí mi sí, kí èmi kí ó lè jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ rẹ fún ìgbàlà àti ìpamọ́ àwọn ènìyàn yíi. Nísisìyí, nígbàtí Álmà ti sọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó tún lọ bá Ámlísì jà; a sì fún un ní ágbára, tóbẹ̃ tí ó pa Ámlísì pẹ̀lú idà. Ó sì tún bá ọba àwọn ará Lámánì jà; ṣùgbọ́n ọba àwọn ará Lámánì sá padà kúrò níwájú Álmà, ó sì rán àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ láti bá Álmà jà. Ṣùgbọ́n Álmà, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀, bá àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Lámánì jà títí nwọn fi pa nwọ́n tí nwọ́n sì lé nwọn padà. Ó sì pa ilẹ̀ nã mọ́, tàbí kí a wípé bèbè nã, èyítí ó wà ní ìhà ìwọ oòrùn odò Sídónì, ó sì ju òkú àwọn ará Lámánì tí a ti pa sínú omi Sídónì, kí àwọn ènìyàn rẹ̀ lè rí ọ̀nà láti kọjá lọ bá àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Ámlísí jà ní ìhà ìwọ oòrùn odò Sídónì. Ó sì ṣe, nígbàtí nwọ́n sì ti dá odò Sídónì kọjá, ni àwọn ará Lámanì àti àwọn ará Ámlísì bẹ̀rẹ̀sí sálọ kúrò níwájú nwọn, l’áìṣírò nwọ́n pọ̀ púpọ̀ tó bẹ̃ tí a kò lè kà nwọ́n. Nwọ́n sì sá kúrò níwájú àwọn ará Nífáì síhà aginjù tí ó wà ní apá ìwọ oòrùn àti apáàríwá, jáde kúrò ní agbègbè ilẹ̀ nã; àwọn ará Nífáì sì lé nwọn pẹ̀lú agbára nwọn, nwọ́n sì pa nwọ́n. Bẹ̃ni, nwọ́n kọlũ nwọ́n ní gbogbo ọ̀nà, nwọ́n pa nwọ́n, nwọ́n sì lé nwọn lọ, títí nwọ́n fi túká ní apá ìwọ oòrùn, àti ní apá gúsù, títí nwọ́n fi dé inú aginjù èyítí nwọ́n pè ní Hámọ́ntì; eleyĩ sì ni apá aginjù nã tí ó kún fún àwọn ẹranko búburú. Ó sì ṣe, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kú nínú aginjù fún ọgbẹ́ nwọn, tí àwọn ẹranko búburú nnì sì jẹ nwọ́n, pẹ̀lú àwọn igún ojú ọ̀run; nwọ́n sì ti ri àwọn egungun nwọn, nwọ́n sì kó nwọn jọ sórí ilẹ̀. 3 Àwọn Ámlísì ti ṣe àmì sí ára wọn gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀—Àwọn ará Lámánì ti di ẹni-ìfibú fún ìṣọ̀tẹ̀ nwọn—Ènìyàn ni ó nmú ìfibú wá sí órí ara nwọn—Àwọn ará Néfáí borí ẹgbẹ́ ọmọ ogun miran ti àwọn ará Lámánì. Ní ìwọ̀n ọdún 87 sí 86 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Nífáì tí a kò pa nipa awọn ohun ìjà ogun, lẹhin tí nwọ́n ti sin àwọn tí a pa—nísisìyí a kò ka iye àwọn tí a pa nítorítí nwọ́n pọ̀ pupọ̀—lẹ́hìn tí nwọ́n ti sin àwọn tí ó kú tán, gbogbo nwọn padà sí ilẹ̀ nwọn, àti sí ilé nwọn, àti àwọn aya nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn. Nísisìyí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọdé ni a ti pa pẹ̀lú idà, àti pẹ̀lú púpọ̀ nínú àwọn agbo-ẹran àti ọwọ́-ẹran nwọn; àti pẹ̀lú púpọ̀ nínú àwọn oko wóró irúgbìn nwọn ni a run, nítorítí ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn tẹ̀ nwọ́n pa. Àti nísisìyí, gbogbo àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Ámlísì tí a ti pa ní bèbè odò Sídónì ni a sọ sínú omi Sídónì; sì kíyèsĩ egungun nwọn wà ní ìsàlẹ̀ òkun, nwọ́n sì pọ̀. Àwọn ará Ámlísì wà ní ìdáyàtọ̀ kúrò lãrín àwọn ará Nífáì, nítorítí nwọ́n ti kọ ara nwọn ní àmì pupa ní iwájú orí nwọn, gẹ́gẹ́bí ìṣe àwọn ará Lámánì; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọn kò fá orí nwọn gẹ́gẹ́bí àwọn ará Lámánì ti ṣe. Nísisìyí, àwọn ará Lámánì fárí, nwọn kò sì wọ aṣọ, àfi awọ tí nwọ́n sán mọ́ ìbàdí, àti ìhámọ́ra nwọn pẹ̀lú, èyítí nwọ́n sán mọ́ra, àti ọrún nwọn, àti ọfà nwọn, àti òkúta-wẹ́wẹ́ nwọn, àti kànnà-kànnà nwọn, àti bẹ̃ bẹ̃ lọ. Àwọ̀ ara àwọn ará Lámánì sì sú, gẹ́gẹ́bí àmì tí a ti fi lé àwọn bàbá nwọn lára, èyítí íṣe ìfibú lórí nwọn, nítorí ìwàìrékọjá nwọn, àti ìṣọ̀tẹ̀ nwọn sí àwọn arákùnrin nwọn, tí nwọn íṣe Nífáì, Jákọ́bù, Jósẹ́fù, àti Sãmú, tí nwọ́n jẹ́ ènìyàn títọ àti ẹni mímọ́. Tí àwọn arákùnrin nwọn lépa láti pa nwọ́n run, nítorínã ni a fi fi nwọ́n bú; tí Olúwa Ọlọ́run sì fi àmì lé nwọn lára, bẹ̃ni sí órí Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì, àti àwọn ọmọ Íṣmáẹ́lì pẹ̀lú, àti àwọn obìnrin ilé Íṣmáẹ́lì. A sì ṣe eleyĩ kí a lè mọ́ irú ọmọ wọn lãrín irú-ọmọ àwọn arákùnrin wọn pé nípa èyí nã Olúwa Ọlọ́run yíò pa àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́, tí nwọn kò sì ní dàpọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin nwọn,kí nwọ́n sì gba àṣà tí kò tọ̀nà gbọ́, èyítí yíò jẹ́ ìparun fún nwọn. Ó sì ṣe, wípé ẹnìkẹ́nì tí ó bá da irú-ọmọ rẹ̀ pọ̀ mọ́ ti àwọn ará Lámánì mú ìfibú kannã sí órí irú-ọmọ tirẹ̀. Nítorínã, ẹnìkẹ́ni tí ó bá jẹ́ kí àwọn ará Lámánì ṣi òun lọ́nà ni nwọ́n npè ni ábẹ́ àmì yíi, a sì fi àmì nã lée. Ó sì ṣe wípé ẹnìkẹ́ni tí kò bá gbàgbọ́ nínú àṣà àwọn ará Lámánì, ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ nínú àwọn ìwé ìrántí tí a mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, àti nínú àṣà àwọn bàbá nwọn, èyítí ó pé, tí ó gbàgbọ́ nínú awọn òfin Ọlọ́run tí ó sì pa nwọ́n mọ́, ni a pè ní àwọn ará Nífáì, tàbí àwọn ènìyàn Nífáì, láti ìgbà nã lọ— Àwọn sì ni ó ti tọ́jú àwọn ìwé ìrántí tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn ènìyàn nwọn, àti pẹ̀lú nípa àwọn ará Lámánì. Nísisìyí, àwa yíò tún padà sórí àwọn ará Ámlísì, nítorítí àwọn nã ní àmì tí a fi lé nwọn lára; bẹ̃ni, nwọ́n sì fi àmì nã lé ara nwọn, bẹ̃ni, àní àmì pupa lé iwájú orí nwọn. Báyĩ gẹ́gẹ́ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di mímúṣẹ, nítorípé àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí ó bá Nífáì sọ: Kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì ni èmi ti fi bú, èmi yíò sì fi àmì lé nwọn lára, pé àwọn pẹ̀lú àwọn irú ọmọ nwọn, ni a o pín níyà kúrò lãrín ìwọ àti àwọn irú-ọmọ rẹ, láti ìsisìyí lọ, àti títí láéláé, àfi tí nwọn bá ronúpìwàdà kúrò nínú ìwà búburú wọn, kí nwọ́n sì padà tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè ṣãnú fún nwọn. Àti pẹ̀lú: Èmi yíò fi àmì lé ẹni nã tí ó bá da irú-ọmọ rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin rẹ pé kí a fi nwọ́n bú pẹ̀lú. Àti pẹ̀lú: Èmi yíò fi àmì lé ẹni nã tí ó bá bá ọ jà àti irú-ọmọ rẹ. Àti pẹ̀lú, èmi wípé ẹni nã tí ó bá yapa kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a kò lè pè ní èso rẹ mọ́; èmi yíò sì bùkún fún ọ, àti fún ẹnikẹ́ni tí a pè ní èso rẹ, láti ìsisìyí lọ àti láéláé; àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ìlérí Olúwa sí Nífáì àti sí irú ọmọ rẹ̀. Nísisìyí àwọn ará Ámlísì kò sì mọ̀ wípé àwọn nmú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ré kọjá ni, nígbàtí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí fi àmì lé iwájú orí ara nwọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n ti jáde wá ní ìṣọ̀tẹ ní gbangba si Ọlọ́run; nítorínã, ó jẹ́ ohun ẹ̀tọ́ kí ègún nã kí ó ré lù nwọ́n. Nísisìyí, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó ríi pé àwọn ni nwọ́n fa ègún nã sí órí àra nwọn; àti pé bẹ̃ni gbogbo ẹni tí a bá ti fi gé ègún ni ó mú ìdánilẹ́bi wá sí órí ara rẹ̀. Nísisìyí, ó sì ṣe tí kò pẹ́ lẹ́hìn ìjà tí nwọ́n jà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, lãrín àwọn ara Lámánì àti àwọn ará Ámlísì, tí ẹgbẹ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì míràn tún ṣí ti àwọn ará Nífáì, ní ojú ibi tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun àkọ́kọ́ ti pàdé àwọn ará Ámlísì. Ó sì ṣe tí a rán àwọn ọmọ ogun kan láti lé nwọn jáde kúrò lórí ilẹ̀ nwọn. Nísisìyí Álmà fúnrãrẹ nítorítí ó gbọgbẹ́, kò lọ sí ójú ogun ní àkókò yí láti dojúkọ àwọn ará Lámánì; Ṣùgbọ́n ó rán àwọn ogunlọ́gọ̀ ọmọ ogun sí nwọn; nwọn sì lọ, nwọ́n sì pa púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì lé àwọn tí ó kù nínú nwọn jáde kúrò ní agbègbè ilẹ̀ nwọn. Nwọ́n sì tún padà, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí fi àlãfíà lélẹ̀ ní ilẹ̀ nã, tí àwọn ọ̀tá nwọn kò sì yọ nwọ́n lẹ́nu mọ́ fún ìgbà kan. Nísisìyí, gbogbo ohun wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀, bẹ̃ni, gbogbo àwọn ogun àti ìjà yíi bẹ̀rẹ̀ nwọ́n sì parí ní ọdún kãrún ní ìjọba àwọn onídàjọ́. Nínú ọdún kan sí ní ẹgbẹ̀rún àti ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ẹ̀mí kọjá lọ sí ayé àìnípẹ̀kun, kí nwọ́n lè kórè gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ nwọn, bí ó jẹ́ rere, tàbí ó jẹ́ búburú, kí nwọ́n lè kórè ayọ̀ àìnípẹ̀kun, tàbí ìrora àìnípẹ̀kun, gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí tí nwọ́n gbọ́ran sí, bí ó jẹ́ ẹ̀mí dáradára tàbí búburú. Nítorípé gbogbo ènìyàn yíò gba èrè lọ́wọ́ ẹni tí òun gbọ́ran sí, èyí sì jẹ́ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀; nítorínã, jẹ́ kí ó rí bẹ̃ gẹ́gẹ́bí òtítọ́. Báyĩ sì ni ọdún kãrún ìjọba àwọn onídàjọ́. 4 Álmà ri ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àwọn ẹnití a yí lọ́kàn padà bọmi—Àìṣedẽdé wọ inú ìjọ, ìfàsẹ́hìn sì dé bá ìjọ—A yan Néfáíhà gẹ́gẹ́bí onídàjọ́ àgbà—Álmà, gẹ́gẹ́bí olórí àlùfã, ṣe ìfọkànsìn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ní ìwọ̀n ọdún 86–83 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí ó sì ṣe ní ọdún kẹfà nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, kò sí ìjà tàbí ogun ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn nã ní ìpọ́njú, bẹ̃ni, ìpọ́njú nlá lórí ìpàdánù àwọn arákùnrin nwọn, àti pẹ̀lú fún ìpàdánù àwọn agboẹran nwọn àti àwọn ọ̀wọ́-ẹran nwọn, àti fún ìpàdánù àwọn pápá ọkà nwọn, èyítí àwọn ará Lámánì tẹ̀ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ nwọn, tí wọ́n sì parun. Báyĩ sì ni ìpọ́njú nwọn pọ̀ tó, tí ó jẹ́ wípé gbogbo ènìyàn ni ó níláti ṣọ̀fọ̀; nwọ́n sì gbàgbọ́ wípé ìdájọ́ Ọlọ́run ni a rán lé nwọn lórí nítorí àìṣedẽdé nwọn àti ìwà ìríra nwọn; nítorínã nwọ́n sì tají sí ìrántí iṣẹ́ ẹ̀sìn nwọn. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí dá ìjọ sílẹ̀ síi; bẹ̃ni, ọ̀pọ̀ ni a sì rìbọmi nínú omi Sídónì, a sì dà nwọ́n pọ̀ mọ́ ìjọ-Ọlọ́run; bẹ̃ni, a rì nwọn bọmi láti ọwọ́ Álmà, èyítí a ti yà sí mímọ́ sí ipò olórí àlùfã lórí àwọn ènìyàn ìjọ nã, láti ọwọ́ bàbá rẹ̀, Álmà. Ó sì ṣe, ní ọdún keje nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ẹ̃dẹ́gbẹ̀ta ènìyàn da ara pọ̀ mọ́ ìjọ Ọlọ́run tí a sì rì nwọn bọmi. Báyĩ sì ni ọdún keje nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ dé òpin lórí àwọn ènìyàn Nífáì; àlãfíà sì wà ní gbogbo ìgbà nã. Ó sì ṣe, ní ọdún kẹjọ ti ìjọba àwọn onídàjọ́, tí àwọn ará ìjọ nã bẹ̀rẹ̀síi ṣe ìgbéraga nítorí ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí nwọ́n ní, àti aṣọ dáradára nwọn àti aṣọ olówó-iyebíye nwọn, àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbo-ẹran àti ọ̀wọ́-ẹran nwọn, àti wúrà nwọn àti fàdákà nwọn, àti onírurú ohun iyebíye, èyítí nwọ́n ti ní nípa ìtẹpámọ́ṣẹ́, nínú ohun wọ̀nyí ni nwọ́n sì rú ara nwọn sókè ní ìgbéraga, nítorítí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí wọ aṣọ olówó-iyebíye. Nísisìyí èyí ni ohun tí ó fa ìpọ́njú fún Álmà, bẹ̃ni, àti fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí Álmà ti yà sọ́tọ̀ láti jẹ́ olùkọ́ni, àti àlùfã, àti àwọn àgbàgbà lórí ìjọ nã; bẹ̃ni, púpọ̀ nínú nwọn kẹ́dùnnítorí àìṣedẽdé tí nwọ́n rí tí ó ti bẹ̀rẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn wọn. Nítorítí nwọ́n ṣàkíyèsí pẹ̀lú ìbànújẹ́ pé àwọn ènìyàn ìjọ nã bẹ̀rẹ̀sí gbé ara nwọn sókè nínú ìgbéraga ojú nwọn, àti láti gbe ọkàn nwọn le ọrọ̀ àti ohun asán ayé, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pẹ̀gàn ara nwọn, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe inúnibíni sí àwọn tí nwọn kò gbàgbọ́ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti ìdùnnú nwọn. Àti báyĩ, ní ọdún kẹjọ nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, ìjà púpọ̀ sì bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín àwọn ènìyàn ìjọ nã; bẹ̃ni, ìlara, ìjà, pẹ̀lú àrankàn, àti inúnibĩni, àti ìgbéraga, ni ó wà pẹ̀lú, àní tí ó tayọ ìgbéraga àwọn tí nwọn kì íṣe ará ìjọ ti Ọlọ́run. Báyĩ sì ni ọdún kẹjọ ìjọba àwọn onídàjọ́ parí; ìwà búburú ìjọ nã sì jẹ́ ohun-ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn tí kì íṣe ará ìjọ nã; báyĩ sì ni ìjọ nã bẹ̀rẹ̀sí kùnà nínú ìtẹ̀síwájú rẹ̀. Ó sì ṣe, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹẹ̀sán, Álmà rí ìwà búburú ìjọ nã, òun sì ríi tí àpẹrẹ ìjọ nã bẹ̀rẹ̀sí darí àwọn aláìgbàgbọ́ lati ìwà àìṣedẽdé kan sí òmíràn, tí ó sì mú ìparun bá àwọn ènìyàn nã. Bẹ̃ni, òun rí àìdọ́gba tí ó tóbi lãrín àwọn ènìyàn nã, àwọn kan sí gbé ara nwọn sókè nínú ìgbéraga nwọn, tí nwọn nkẹ́gàn àwọn míràn, tí nwọ́n sì nṣe ìkórira àwọn aláìní, àti àwọn tí ó wà ní ìhọ́hò, ati àwọn ti ebi npa, àti àwọn tí npòngbẹ, àti àwọn tí nwọ́n ṣàìsàn àti tí ìyà njẹ. Nísisìyí, èyí fa ohun ìpohùnréré- ẹkún lãrín àwọn ènìyàn nã, bí àwọn kan ṣe nrẹ ara nwọn sílẹ̀, tí nwọ́n sì nṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí ó nílò ìrànlọ́wọ́ nwọn nípa fífúnni nínú ohun ìní nwọn fún àwọn tálákà àti àwọn aláìní, tí nwọn nbọ́ àwọn tí ebi npa, tí nwọ́n sì nfarada onírurú ìpọ́njú, nítorí Krístì, ẹnití mbọ̀wá gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀; Tí nwọ́n sì nretí ọjọ́ nã, nípa èyítí nwọ́n rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nwọn; tí nwọ́n sì kún fún ayọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí àjĩnde òkú, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti agbára àti ìdásílẹ̀ Jésù Krístì kúrò lọ́wọ́ ìdè ikú. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Álmà, nígbàtí ó rí ìpọ́njú àwọn onírẹ̀lẹ̀ọkàn tí nwọ́n jẹ́ olùtẹ̀lé Ọlọ́run, àti àwọn inúnibíni tí a dà lé nwọn lórí láti ọwọ́ àwọn èyítí ó ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn rẹ̀, tí ó sì rí gbogbo àìdọ́gba nwọn, ó sì bẹ̀rẹ̀sí banújẹ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃ Ẹ̀mí Olúwa kò jáa kulẹ̀. Ó sì yan ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan, ẹniti ó wà lãrín àwọn àgbàgbà ìjọ nã, ó sì fún un ní agbára gẹ́gẹ́bí ohùn àwọn ènìyàn, pé kí ó lè ní agbára láti fi òfin lélẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn òfin èyítí a ti fún nwọn, kí o sì fi nwọ́n múlẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn nã. Nísisìyí, orúkọ ọkùnrin yíi ní Néfáíhà, a sì yàn án ní onídàjọ́ agba; òun sì jókọ́ lórí ìtẹ́ ìdájọ́ láti ṣe ìdájọ́ àti lati ṣe àkóso àwọn ènìyàn nã. Nísisìyí, Álmà kò fún un ní ipò olórí àlùfã lórí ìjọ nã, ṣùgbọ́n ó fi ara rẹ̀ sí ipò olórí àlùfã; ṣùgbọ́n ó fi ìtẹ́ ìdájọ́ lé Néfáíhà lọ́wọ́. Èyí ni ó sì ṣe, kí òun fúnrarẹ̀ lè kọjá lọ lãrín àwọn ènìyàn rẹ, tabi larin àwọn ènìyàn Nífáì, kí òun kí ó lè kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí nwọn, láti ta nwọ́n jí ní ìrántí iṣẹ́ ìsìn nwọ́n, àti kí ó lè já kulẹ̀, nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbogbo ìgbéraga àtiọgbọ́n àrékérekè àti gbogbo ìjà tí ó wà lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorítí kò rí ọ̀nà míràn tí ó fi lè gbà nwọ́n, àfi nípa jíjẹ́ ẹ̀rí ìgbàgbọ́ sí nwọn. Báyĩ ni, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹẹ̀sán nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, lórí àwọn ará Nífáì, Álmà gbé ìtẹ́ ìdájọ́ sílẹ̀ lé Néfáíhà lọ́wọ́, ó sì fi ara rẹ̀ sílẹ̀ pátápátá fún iṣẹ́ oyè-àlùfã gíga, èyítí íṣe ti ẹgbẹ́ mímọ́ ti Ọlọ́run, fún ẹ̀rí ọ̀rọ̀ nã, gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ti ìfihàn àti ti ìsọtẹ́lẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Álmà, ẹ̀nití íṣe Olórí Àlùfã gẹ́gẹ́bí ti ẹgbẹ́ mímọ́ Ọlọ́run, fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn nínú àwọn ìlú ńlá àti ìletò nwọn jákè-jádò ilẹ̀ nã. Èyítí a kọ sí orí 5. 5 Lati lè rí ìgbàlà, ènìyàn gbọdọ̀ ronúpìwàdà, kí ó sì pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí ó di àtúnbí, kí ó fọ aṣọ rẹ̀ mọ̀ nípa ẹ̀jẹ̀ Krístì, kí ó ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn, kí ó sì bọ́ ẹ̀wù ìgbéraga àti ìlara sílẹ̀, kí ó sì máa ṣe iṣẹ́ òdodo—Olùṣọ́-Àgùtàn Rere npe àwọn ènìyàn rẹ̀—Àwọn tí nwọ́n bá nṣe iṣẹ́ búburú ní íṣe ọmọ èṣù—Álmà jẹ́ ẹ̀rí sí òtítọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ó sì pã láṣẹ pé kí àwọn ènìyàn ronúpìwàdà—Orúkọ àwọn olódodo ni a ó kọ sínú ìwé ìyè. Ní ìwọ̀n ọdún 83 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí ó sì ṣe tí Álmà bẹ̀rẹ̀sí fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn nã, ní àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã. Àwọn wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún àwọn ènìyàn ìjọ-onígbàgbọ́ èyítí a dá sílẹ̀ nínú ìlú nlá Sarahẹ́múlà, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ rẹ̀, tí ó wípé: Èmi, Álmà, ẹnití bàbá mi, Álmà ti yà sọ́tọ̀ láti jẹ́ olórí àlùfã lórí ìjọ-Ọlọ́run, ẹnití ó ní agbára àti àṣẹ láti ọwọ́ Ọlọ́run fún ṣíṣe àwọn ohun wọ̀nyí, kíyèsĩ, Èmi wí fún yín pé òun bẹ̀rẹ̀sí dá ìjọ sílẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà ilẹ̀ Nífáì; bẹ̃ni, ilẹ̀ èyítí à npè ní ilẹ̀ ti Mọ́mọ́nì; bẹ̃ni, òun sì ri àwọn arákùnrin rẹ̀ bọmi nínú omi Mọ́mọ́nì. Sì kíyèsĩ, mo wí fún yín, a kó nwọn yọ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ọba Nóà, nípa ãnú àti agbára Ọlọ́run. Sì kíyèsĩ, lẹ́hìn èyíi nì, a mú nwọn wá sínú ìgbèkùn nípa ọwọ́ àwọn ará Lámánì nínú aginjù; bẹ̃ni, mo wí fún yín, nwọ́n wà nínú oko-ẹrú, Olúwa sì tún kó nwọn yọ kúrò nínú oko-ẹrú nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀; Olúwa sì mú wa jáde wá sínú ilẹ̀ yí, ní ìhín yĩ ni àwa sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìdásílẹ̀ ìjọ-Ọlọ́run jákè-jádò ilẹ̀ yí pẹ̀lú. Àti nísisìyí kíyèsĩ, èmi wí fún un yín, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀yin tí íṣe ti ìjọ-onígbàgbọ́ yĩ, njẹ́ ẹ̀yin ní ìrántí tí ó péye tó nípa ìgbèkun àwọn bàbá nyín? Bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin ní ìrántí tí ó péye nípa ãnú àti ìpamọ́ra rẹ̀ sí nwọn? Síbẹ̀síbẹ̀ pẹ̀lú, njẹ́ ẹ̀yin ní ìràntí tí ó péye pé òun ti gba ẹ̀mí nwọn kúrò nínú ọ̀run-àpãdì? Kíyèsĩ, ó yí ọkàn nwọn padà; bẹ̃ni, ó ta nwọ́n jí kúrò nínú ọ́run àsùnwọra, nwọn sì tají sí ìpè Ọlọ́run. Kíyèsĩ, nwọ́n wà nínú òkùnkùn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, atan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn nwọn nípa ìmọ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ ayérayé; bẹ̃ni ìdè ikú yí nwọn ká, pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n ọ̀run-àpãdì, ìparun ayérayé sí dúró dè nwọ́n. Àti nísisìyí, èmi bí yín, ẹ̀yin arákùnrin mi, njẹ́ a pa nwọ́n run? Kíyèsĩ èmi wí fún un yín, Rárá, a kò pa nwọ́n run. Èmi tún bí yín, njẹ́ ìdè ikú já? Pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n ọ̀run-àpãdì tí ó dè nwọ́n, njẹ́ a tú nwọn? Èmi wí fún un yín, bẹ̃ni, nwọ́n di títú, ọkàn nwọn sì kún fún ayọ̀ àti inú dídùn, nwọ́n sì kọrin ìfẹ́ ti ìràpadà. Èmi sì wí fún yín pé a gbà nwọ́n là. Àti nísisìyí èmi bí yín pé báwo ni nwọ́n ṣe di ẹni ìgbàlà? Bẹ̃ni, báwo ni nwọ́n ṣe ní ìrètí fún ìgbàlà? Kíni ìdí tí a fi tú nwọn sílẹ̀ nínú ìdè ikú, bẹ̃ni, àti ẹ̀wọ̀n ọ̀run-àpãdì pẹ̀lú? Kíyèsĩ, èmi lè sọ fún un yín—njẹ́ bàbá mi Álmà kò ha gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ ti a sọ láti ẹnu Ábínádì? Njẹ́ kĩ ha íṣe wòlĩ mímọ́? Njẹ́ kò ha sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ti Bàbá mi Álmà sì gbã wọ́n gbọ́? Gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ pẹ̀lú, àyípadà nlá sì bá ọkàn rẹ̀, kíyèsĩ, èmi wí fún un yín pé òtítọ́ ni gbogbo nkan wọ̀nyí. Sì kíyèsĩ, ó kéde ọ̀rọ̀ nã fún àwọn bàbá a yín, àyípadà nlá sì bá ọkàn nwọn, nwọ́n sì rẹ ọkàn nwọn sílẹ̀, nwọ́n sì gbẹ́kẹ̀ nwọn l é Ọlọ́run ò t í t ọ́ à t i alãyè. Sì kíyèsĩ, nwọ́n jẹ́ olótĩtọ́ títí dé òpin; nítorínã ni a ṣe gbà nwọ́n là. Àti nísisìyí kíyèsĩ, mo bẽrè lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin arákùnrin mi nínú ìjọ onígbàgbọ́, njẹ́ a ti bí yin ní ti ẹ̀mí nípa ti Ọlọ́run? Njẹ́ ẹ̀yin ti gba àwòrán rẹ nínú ìrísí yín? Njẹ́ ẹ̀yin ti ní ìrírí ìyípadà nlá yìi ní ọkàn yín bí? Njẹ́ ẹ̀yin ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà ẹni nã tí ó dáa yín? Njẹ́ ẹ̀yin nwo iwájú pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́, tí ẹ̀yin sì nwòye ara kíkú yĩ tí a gbé dìde ní aìkú, àti ara ìdibàjẹ́ yĩ tí a gbé dìde ní àìdíbàjẹ́, kí ẹ̀yin lè dúró níwájú Ọlọ́run fún ìdájọ́ lórí àwọn ohun tí a ti ṣe nínú ara kíkú? Èmi wí fún yín, njẹ́ ẹ̀yin lè wòye pé ẹ gbọ́ ohùn Olúwa, tí yíò wí fún yín, ní ọjọ́ nã: Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin alábùkún-fún, nítorí kíyèsĩ, àwọn iṣẹ́ rẹ ti jẹ́ iṣẹ́ òdodo ni orí ilẹ̀ ayé? Bóyá ẹ̀yin lérò wípé ẹ̀yin lè purọ́ níwájú Olúwa ní ọjọ́ nã, kí ẹ̀yin sì wípé—Olúwa, òdodo ni àwọn iṣẹ́ wa ní orí ilẹ̀ áyé—tí òun yíò sì gbà yín là? Tàbí, ẹ̀wẹ̀, njẹ́ ẹ̀yin wòye pé tí a bá mú un yín wá sí iwájú ìdájọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú ọkàn an yín tí ó kún fún ẹ̀bi àti àbámọ̀, tí ẹ̀yin sì ní ìrántí fún gbogbo ẹ̀bi yín, bẹ̃ni, ìrántí tí ó yè koro fún gbogbo ìwà búburú u yín, bẹ̃ni, ìrántí pé ẹ̀yin ti ṣe àìbìkítà àwọn òfin Ọlọ́run? Èmi wí fún un yín, njẹ́ ẹ̀yin le gbe ojú sókè si Ọlọ́run ni ọjọ naa pẹlu ọkan mimọ ati ọwọ ti ko ni èérí? Mo wi fun yin, njẹ́ ẹ̀yin lè gbé ojú sókè, wípé ẹ̀yà àwòrán Ọlọ́run ti di fífín sí ìrísí nyín? Mo wí fún un yín, njẹ́ ẹ̀yin lè gbèrò láti rí ìgbàlà nígbàtí ẹ̀yin ti jọ̀wọ́ ara yín láti jẹ́ ọmọ-lẹ́hìn èṣù bí? Mo wí fún yín, ẹ̀yin yíò mọ̀ ní ọjọ́ nnì pé ẹ̀yin kò lè rí ìgbàlà;nítorĩ a kò lè gba ẹnìkẹ́ni là àfi tí a bá sọ ẹ̀wù nwọn di funfun; bẹ̃ni, ẹ̀wù rẹ̀ níláti di mímọ́ títí a ó fi wẹ gbogbo ẽrí kúrò lára nwọn, nípa ẹ̀jẹ̀ ẹni nã ẹnití a ti sọ nípa rẹ̀ láti ẹnu àwọn bàbá wa, ẹnití ó nbọ̀wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn. Àti nísisìyí èmi bẽrè lọ́wọ́ ọ yín, ẹyin arákùnrin mi, báwo ni ẹnìkẹ́ni nínú u yín yíò ṣe rò, tí ẹ bá dúró níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, tí aṣọ yín sì ní àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ àti onírurú ẹ̀gbin? Wòo, kí ni àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́rĩ sí nípa yín? Ẹ kíyèsĩ njẹ́ nwọn kò ní jẹ́rĩ pé apànìyàn ni ẹ̀yin íṣe, bẹ̃ni, àti pé ẹ̀yin jẹ̀bi onírũrú ìwà búburú bí? Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, njẹ́ ẹ̀yin lérò pé irú ẹni báyĩ ni ãyè láti jókọ́ nínú ìjọba Ọlọ́run, pẹ̀lú Ábráhámù, pẹ̀lú Ísãkì, ati pẹ̀lú Jákọ́bù, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́, tí aṣọ nwọn ti mọ́, tí nwọ́n sì wà láìlẽrĩ, láìlábàwọ́n àti ní funfun? Mo wí fún yín, Rárá; àfi bí ẹ̀yin bá mú Ẹlẹ́dã wa ní èké láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, tàbí kí ẹ rò pé èké ni íṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ wá ẹ̀yin kò ní èrò pé irú eleyĩ lè ní ãyè nínú ìjọba ọ̀run; ṣùgbọ́n a ó ta wọ́n nù, nítorítí ọmọ ìjọba èṣù ni wọn íṣe. Àti nísisìyí kíyèsĩ, mo wí fún un yín, ẹ̀yin arákùnrin mi, tí ẹ̀yin bá ti rí ìyípadà ọkàn, tí ẹ̀yin bá sì fẹ́ láti kọ orin ìfẹ́ ti ìràpadà, mo bẽrè, njẹ́ ẹ̀yin sì fẹ́ bẹ̃ bí? Njẹ́ ẹ̀yin ha ti nrìn, tí ẹ sì npa ara nyín mọ́ láìlẹ́bi níwájú Ọlọ́run? Njẹ́ ẹ̀yin lè sọ, nínú ọkàn an yín, tí a bá yàn an fún un yín láti kú ní báyĩ, pé ẹ̀yin ti rẹ ara yín sílẹ̀ tó bẹ̃? Pé aṣọ ọ yín ti wà láìlẽrĩ, ó sì ti di funfun nípa ẹ̀jẹ̀ Krístì, ẹnití yíò wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀? Ẹ kíyèsĩ, njẹ́ ẹ̀yin ti bọ́ èwù ìgbéraga sílẹ̀? Mo wí fún yín, tí kò bá rí bẹ̃ ẹ̀yin kò ì tĩ ṣetán láti bá Ọlọ́run pàdé. Kíyèsĩ ẹ̀yin níláti múrasílẹ̀ ní kánkán; nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀, irú eleyĩ kò sì ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ kíyèsĩ, mo wípé, njẹ́ a rí nínú yín ẹnití kò bọ́ ẹ̀wù ìlara? Mo wí fún yín pé eleyĩ kò tĩ múrasílẹ̀; èmi sì rọ̣́ pé kí ó múrasílẹ̀ kánkán, nítorítí wákàtí nã ti dé tán, òun kò sì mọ́ àkokò tí ìgbà nã yíò dé; nítorítí a kò ní ṣe aláì dá eleyĩ lẹ́bi. Èmi sì tún wí fún yín, njẹ́ a rí nínú u yín ẹnití ó nfi arákùnrin rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà, tàbí tí ó nṣe inúnibíni sí bí? Ègbé ni fún eleyĩ, nítorítí kò wà ní ìmúrasílẹ̀, àkokò nã sì ti dé tán tí o níláti ronúpìwàdà, bí kò rí bẹ̃, a kò lè gbã là! Bẹ̃ni, ègbé ni fún gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ ẹ̀ṣẹ̀; ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà, nítorítí Olúwa Ọlọ́run ni ó wíi ! Ẹ kíyèsĩ, ó rán ìpè sí gbogbo ènìyàn, nítorípé ó na ọwọ́ ãnú rẹ̀ sí nwọn, òun sì wípé: Ẹ ronúpìwàdà, èmi yíò sì gbà yín. Bẹ̃ni, ó wípé: Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ̀yin yíò sì pín nínú èso igi ìyè nã; bẹ̃ni, ẹ̀yin yíò jẹ, ẹ ó mú nínú oúnjẹ àti omi ìyè nã lọ́fẹ̃; Bẹ̃ni, ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí ẹ sì mú iṣẹ́ ìṣòdodo yín wá, a kò sì ní kée yín lulẹ̀ kí a sì sọ yín sínú iná— Nítorí ẹ kíyèsĩ, àkokò nã ti dé tán tí ẹnìkẹ́ni tí kò bá mú èso rere jáde wá, tàbí ẹnìkẹ́ni tí kò bá ṣe iṣẹ́ rere, eleyĩ ni yíò pohùnréré ẹkún, tí yíò ṣọ̀fọ̀. A! ẹ̀yin aláìṣedẽdé; ẹ̀yin tí ẹ gbé ọkàn an yín sókè nínú àwọn ohun asán ayé, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́wọ́ tẹ́lẹ̀rí pé ẹ̀yin ti mọ́ ọ̀nà òdodo, bíótilẹ̀ríbẹ̃ tí ẹ ti ṣáko lọ, gẹ́gẹ́bí àgùtàn tí kò ní olùṣọ́, l’áìṣírò, olùṣọ́-àgùtàn ti ké pè yín, ó sì nké pè yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tí sí ohùn rẹ̀! Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín, pé olùṣọ́-àgùtàn rere nã npè yín; bẹ̃ni, ní orúkọ rẹ̀ ni ó npè nyín, èyítí íṣe orúkọ Krístì, tí ẹ̀yin kò bá sì gbọ́ ohùn olùṣọ́-àgùtàn rere nã, sí orúkọ nã, èyítí a fi npè yín, kíyèsĩ, ẹ̀yin kĩ ṣe àgùtàn ti olùṣọ́-àgùtàn rere nã. Àti nísisìyí, tí ẹ̀yin kò bá íṣe àgùtàn ti olùṣọ́-àgùtàn rere nã, agbo tani ẹ̀yin íṣe? Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún un yín, pé èṣù ni olùṣọ́-àgùtàn yín, ẹ̀yin sì ni agbo rẹ̀; àti nísisìyí, tani ó lè sẹ́ eleyĩ? Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín, ẹnìkẹ́ni tí ó bá sẹ eleyĩ, èké ni, ọmọ èṣù sì ni. Nítorínã ni mo ṣe wí fún un yín pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá jẹ́ dáradára, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ó ti wá, ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì jẹ́ búburú, ọ̀dọ̀ èṣù ni ó ti wá. Nítorínã, tí ènìyàn bá mú iṣẹ́ rere jáde wá, ó ngbọ́ràn sí ohùn olùṣọ́-àgùtàn rere, ó sì ntẹ̀lée; ṣùgbọ́n ẹnìkẹ́ni tí ó bá nmú iṣẹ́ búburú jáde, èyí kannã ló di ọmọ èṣù, nítorítí ó ngbọ́ràn sí ohùn rẹ̀, ó sì ntẹ̀lée. Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì nṣe eleyĩ níláti gba èrè láti ọwọ́ rẹ̀; nítorínã, fún èrè iṣẹ́ rẹ̀, yíò gba ikú nípa àwọn ohun tí íṣe ti ìwà òdodo, nítorítí ó ti kú nínú gbogbo iṣẹ́ rere. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi rọ̀ yín pé kí ẹ gbọ́ mi, nítorítí èmi nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára ẹ̀mí mi; nítorí kíyèsĩ, èmi ti bá yín sọ̀rọ̀ dájúdájú, tí ẹ̀yin kò sì lè kọsẹ̀, tàbí pé èmi ti sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́bí ìpaláṣẹ Ọlọ́run. Nítorípé a pè mí láti sọ̀rọ̀ báyĩ, nípa ẹgbẹ́ mímọ́ ti Ọlọ́run, èyítí ó wà nínú Krístì Jésù; bẹ̃ni, a pã láṣẹ fún mi láti dúró kí èmi sì jẹ́ ẹ̀rí fún àwọn ènìyàn yíi, nípa àwọn ohun tí àwọn bàbá wa ti sọ nípa àwọn ohun tí nbọ̀ wá. Èyí nìkan kọ́, njẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi mọ̀ nípa àwọn ohun wọ̀nyí fúnra mi? Kíyèsĩ, èmi jẹ́ ẹ̀rí síi fún un yín pé èmi mọ̀ pé àwọn ohun tí èmi ti sọ̀rọ̀ nípa nwọn wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́. Báwo sì ni ẹ̀yin ṣe rò pé èmi mọ́ òtítọ́ nwọn? Ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún un yín pé Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run ni ó fi wọ́n hàn mí. Wọ́, èmi ti gba ãwẹ̀ mo sì ti gbàdúrà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ kí èmi kí ó lè mọ́ ohun wọ̀nyí fúnra mi. Àti nísisìyí èmi sì mọ̀ ọ́ fúnra mi pé òtítọ́ ni nwọ́n; nítorítí Olúwa Ọlọ́run ti fi nwọ́n hàn mí nípa Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀; èyí sì ni ẹ̀mí ìfihàn èyítí ó wà nínú mi. Àti pẹ̀lú, èmi wí fún yín pé báyĩ ni a ti fi hàn mí, pé òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí bàbá wa sọ, àní pãpã nípasẹ̀ ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ èyí tí nbẹ nínú mi, tí ó sì tún jẹ́ nípasẹ̀ ìfihàn agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run. Mo wí fún yín pé èmi mọ̀ fúnra mi pé ohunkóhun tí èmi yíò wí fún yín, nípa èyítí ó nbọ̀wá, jẹ́ òtítọ́; èmi sì wí fúnyín, pé èmi mọ̀ wípé Jésù Krístì nbọ̀wá, bẹ̃ni, Ọmọ nã, tí íṣe Ọmọ-bíbí-kanṣoṣo ti Bàbá, tí ó kún fún ọ́re-ọ̀fẹ́, àti ãnú àti òtítọ́. Ẹ kíyèsĩ, òun ni ó nbọ̀wá tí yíò kó gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ, bẹ̃ni, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkẹ́ni tí ó bá gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ ní ìdúróṣinṣin. Àti nísisìyí, mo wí fún yín pé èyí ní irú ọ̀nà tí a gbà pè mí, bẹ̃ni, láti wãsù sí àwọn arákùnrin mi àyànfẹ́, bẹ̃ni, àti gbogbo ẹni tí ó ngbé inú ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, láti wãsù sí ènìyàn gbogbo, àgbà àti ọmọdé, ẹrú àti òmìnira; bẹ̃ni, mo wí fún yín, ẹ̀yin ogbó, àti ẹ̀yin àgbà, àti ìran tí ó nbọ̀; bẹ̃ni, láti kígbe pè wọn, pé kí wọ́n ronúpìwàdà, kí wọ́n sì di àtúnbí. Bẹ̃ni, báyĩ ni Ẹ̀mí Ọlọ́run wí: Ẹ ronúpìwàdà, gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé, nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀; bẹ̃ni, Ọmọ Ọlọ́run nã nbọ̀wá nínú ògo rẹ̀, nínú ipá, ọlá-nlá, agbára àti ìjọba rẹ̀. Bẹ̃ni, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi wí fún un yín, pé Ẹ̀mí Ọlọ́run wípé: Kíyèsĩ ògo Ọba gbogbo ayé; àti Ọba ọ̀run yíò tàn jáde láìpẹ́ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn gbogbo. Ẹ̀mí Ọlọ́run sì tún sọ fún mi pé, bẹ̃ni, ó nkígbe sí mi pẹ̀lú ohùn rara, pé: Lọ jáde kí o sì wí fún àwọn ènìyàn yí pé—Ẹ ronúpìwàdà, ti ẹ̀yin kò bá sì ronúpìwàdà, ẹ̀yin kó lè jogún ìjọba ọ̀run. Èmi tún wí fún un yín, Ẹ̀mí-Ọlọ́run wípé: Kíyèsĩ, a ti fi ãké lélẹ̀ ní ẹ̀bá gbòngbò igi; nítorínã, igi èyíkéyĩ tí kò bá so èso rere jáde ni a ó ké lulẹ̀, tí a ó sì jũ sínú iná, bẹ̃ni, iná èyítí kò lè kú, àní iná èyítí a kò lè pa. Kíyèsĩ, kí ẹ sì rántí, Ẹní Mímọ́ nã ni ó wíi. Àti nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi wí fún un yín, njẹ́ ẹ̀yin lè ṣe àìbìkítà sí ohun wọ̀nyí; bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin le fo nwọn ru, kí ẹ̀yin sì tẹ Ẹní Mímọ́ nnì mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín; bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin lè ru ọkàn an yín sókè nínú ìgbéraga; bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin yíò ha tún wọ ẹ̀wù olówó iyebíye, kí ẹ̀yin kí ó sì fi ọkàn tán ohun asán ayé àti àwọn ọrọ̀ọ yín? Bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin yíò ha tẹramọ́ èrò ọkàn an yín pé ẹ̀yin dáraju ẹlòmíràn lọ; bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin yíò ha teramọ́ ṣíṣe inúnibíni sí àwọn arákùnrin yín, tí nwọ́n rẹ ara nwọn sílẹ̀ tí nwọ́n sì nrìn ní ẹgbẹ́ ọ̀nà mímọ́ Ọlọ́run, nípasẹ̀ èyítí a ti mú wọn wá sínú ìjọ-onígbàgbọ́ yíi, tí a ti sọ nwọ́n di mímọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́, tí nwọ́n sì nṣe iṣẹ́ èyítí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà— Bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin yíò sì tún tẹramọ́ ṣíṣe ìkóríra àwọn tálákà, àti àwọn aláìní, kí ẹ̀yin sì pa ohun ìní yín mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn? Ní àkótán, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ tẹramọ́ ṣíṣe ìwà búburú, èmi wí fún yín pé àwọn wọ̀nyí ni a ó ke lulẹ̀ tí a ó sì wọ́ nwọn jù sínú iná, àfi tí nwọ́n bá ronúpìwàdà kánkán. Àti nísisìyí mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ṣe àfẹ́rí láti tẹ̀lé ohùn olùṣọ́-àgùtàn rere, ẹ jáde kúrò lãrín àwọn ẹni-búburú, kí ẹ sì ya àrã yín sọ́tọ̀, kí ẹ másì ṣe fi ọwọ́ kan àwọn ohun àìmọ́nwọn; sì kíyèsĩ, a ó pa orúkọ nwọn rẹ́, nítorí orúkọ àwọn ènìyàn búburú ni a kò ní kà mọ́ orúkọ àwọn ènìyàn rere, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ, èyítí ó sọ wípé: Orúkọ àwọn ènìyàn búburu kò ní dàpọ̀ mọ́ orúkọ àwọn ènìyàn mi; Nítorítí a o kọ orúkọ wọn ènìyàn rere sínú ìwé ìyè, àwọn sì ni èmi yíò fún ni ibi ìjòkó ní ọwọ́ ọ̀tún mi. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, kíni ẹ̀yin rí sọ tí ó lòdì sí èyí? Èmi wí fún un yín, tí ẹ̀yin bá sọ̀rọ̀ ìlòdì sí èyí, kò já mọ́ nkankan, nítorípé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ṣẹ. Njẹ́ a rí olùṣọ́-àgùtàn nã lãrín yín, tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgùtàn, tí kò ṣọ́ nwọn, tí ìkokò kì yíò wọlé kí ó pa ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀ jẹ? Sì kíyèsĩ, bí ìkọ́kò bá wọ̀ inú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀ njẹ́ kò ní lée jáde? Bẹ̃ni, ní ìgbẹ̀hìn, tí ó bá ṣeéṣe, yíò pã run. Àti nísisìyí mo wí fún un yín pé olùṣọ́-àgùtàn rere npè yín; tí ẹ̀yin bá sì gbọ́ ohun rẹ̀ òun yíò mú nyín wá sínú agbo rẹ̀, ẹ̀yin sì ni àgùtàn rẹ̀; òun sì pã láṣẹ pé kí ẹ̀yin máṣe gba ìkọ́kò apanirun lãyè láti wọ ãrin yín kí ẹ̀yin kí ó máṣe parun. Àti nísisìyí èmi, Álmà, pã láṣẹ fún un yín ní èdè ẹnití ó ti pã láṣẹ fún mi, pé kí ẹ̀yin kí ó kíyèsí àti ṣe àwọn ọ̀rọ̀ tí èmi ti sọ fún yín. Èmi bá ẹ̀yin tí íṣe ti ìjọ nã sọ̀rọ̀; gẹ́gẹ́bí ìpàṣẹ; àti sí àwọn tí nwọn kĩ ṣe ti ìjọ nã, èmi bã yín sọ̀rọ̀ níti ìpè, wípé: Ẹ wá ṣe ìrìbọmi sí ìrònúpìwàdà, kí ẹ̀yin nã lè di alájọpín nínú èso igi ìyè nã. 6 Ìjọ-onígbàgbọ́ ti Sarahẹ́múlà ni a sọ di mímọ́, tí a sì tọ́ lẹ́sẹsẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà—Álmà lọ sí Gídéónì láti wãsù. Ní ìwọ̀n ọdún 83 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe, lẹ́hìn tí Álmà ti parí ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn ìjọ-onígbàgbọ́ nã, èyítí a dá sílẹ̀ ni ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, ó yan àwọn àlùfã àti àwọn àgbàgbà, nípa gbígbé ọwọ́ lé nwọn lórí gẹ́gẹ́bí ti ẹgbẹ́ Ọlọ́run, kí nwọ́n sì máa ṣe àkóso kí nwọ́n sì máa dábọ́bò ìjọ nã. Ó sì ṣe, pé ẹnìkẹ́ni tí kò bá íṣe ti ìjọ-onígbàgbọ́ nã tí ó bá ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni a rìbọmi sí ìrònúpìwàdà, tí a sì gbà sínú ìjọ nã. Ó sì ṣe tí ẹnìkẹ́ni tí íṣe ti ìjọ nã tí ó bá ṣaláì ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ, tí kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run—Àní mo wípé àwọn tí wọ́n gbé ara nwọn sókè nínú ìgbéraga ọkan wọn—àwọn wọ̀nyí ni a kọ̀, tí a sì pa orúkọ wọn rẹ́, tí a kò sì ka orúkọ wọn mọ́ ti àwọn olódodo. Báyĩ ni nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí dá ìlànà ìjọ-onígbàgbọ́ sílẹ̀ ní ìlú-nlá Sarahẹ́múlà. Nísisìyí èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó ní ìmọ̀ wípé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà fún gbogbo ènìyàn láìyọ ẹnìkan sílẹ̀, pé kò sí ẹni tí a ta dànù fún pípéjọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ọmọ Ọlọ́run ni a paṣẹ fún pé kí wọ́n máa péjọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, kí wọ́n sì darapọ̀ nínú ãwẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà fún àlãfíà ọkàn àwọn tí kò mọ́ Ọlọ́run. Àti nísisìyí, ó sì ṣe, lẹ́hìn tí Álmà ti ṣe àwọn ètò-ìṣàkóso wọ̀nyí ó jáde kúrò lãrín wọn, bẹ̃ni, kúrò ní ìjọ-onígbàgbọ́ èyítí ó wà nínú ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, ó sì lọ sí apá ìlà-oòrùn odò Sídónì, sí àfonífojì Gídéónì, ibi èyítí a ti kọ́ ìlú nlá kan èyítí à npe orúkọ rẹ̀ ní ìlú-nlá Gídéónì, èyítí ó wà ní àfonífojì tí à npè ní Gídéónì, tí a sọọ́ lórúkọ ẹnití a pa láti ọwọ́ Néhórì pẹ̀lú idà. Álmà sì lọ ó sì bẹ̀rẹ̀síi kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ìjọ nã èyítí a dá sílẹ̀ ní àfonífojì Gídéónì, gẹ́gẹ́bí ìfihàn òtítọ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn bàbá rẹ ti sọ, àti gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ èyítí ó ngbé inú rẹ, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ẹnití nbọ̀wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti ti ẹgbẹ́ mímọ́ èyítí a fi pẽ. Báyĩ sì ni a ṣe kọọ́. Àmín. Àwọn ọ̀rọ̀ Álmà èyítí ó sọ fún àwọn ènìyàn tí ó wà ní Gídéónì, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ rẹ̀. Èyítí a kọ sí orí 7. 7 A ó bí Krístì nípasẹ̀ Màríà—Òun yíò já ìdè ikú, yíò sì ru ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀—Àwọn tí nwọ́n bá ronúpìwàdà, tí a sì rìbọmi, tí wọ́n sì pa àwọn òfin mọ́ yíò ní ìyè àìníp ẹ̀ k u n—Ohun ẹ̀ g b i n k ò l è jogún ìjọba Ọlọ́run—Ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ni a bẽrè. Ní ìwọ̀n ọdún 83 kí a tó bí Olúwa wa. Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, níwọ̀n ìgbàtí a ti gbà mí lãyè láti tọ̀ yín wá, nítorínã èmi yíò gbìyànjú láti bã yín sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́bí èdè mi; bẹ̃ni, láti ẹnu mi, níwọ̀n ìgbàtí ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí èmi yíò bã yín sọ̀rọ̀ láti ẹnu mi nítorítí a ti fi mí sí órí ìtẹ́ ìdájọ́, tí èmi sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe tí wọn kò gbà mí lãyè láti wá sí ọ̀dọ̀ yín. Àti pãpã, èmi kì bá má lè wá ní àkokò yĩ, bíkòṣepé a ti fi ìtẹ́ ìdájọ́ fún ẹlòmíràn, láti ṣe ìdájọ́ dípò mi; Olúwa, nínú ọ̀pọ̀ ãnú sì ti gbà kí èmi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ yín. Sì kíyèsĩ, èmi wá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìrètí àti ìfẹ́-inú pé èmi yíò ríi pé ẹ̀yin ti rẹ àrã yín sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, àti pé ẹ̀yin ti tẹ̀síwájú ní títọrọ fún ọ́re-ọ̀fẹ́ rẹ̀, pé èmi yíò bã yín ní àìlẹ́bi níwájú rẹ̀, pé èmi yíò ríi pé ẹ̀yin kò sí nínú ipò búburú nnì nínú èyítí àwọn arákùnrin wa wà ní Sarahẹ́múlà. Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run, pé ó ti fi fún mi láti mọ̀, bẹ̃ni, tí ó sì fún mi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ tí ó tayọ láti mọ̀ pé wọ́n tún ti padà sí ọ̀nà òdodo rẹ̀. Èmi sì ní ìdánilójú, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó wà nínú mi, pé èmi yíò ní ayọ̀ lórí yín; bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi kò fẹ́ kí ayọ̀ mi lórí yín wá nípa ọ̀pọ̀ ìpọ́njú àti ìbànújẹ́ èyítí èmi ti ní fún àwọn arákùnrin tí ó wà ní Sarahẹ́múlà, nítorí ẹ kíyèsĩ, ayọ̀ mi wá lórí wọ́n lẹ́hìn tí wọ́n ti la ìṣòro ìpọ́njú àti ìbànújẹ́ kọjá. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi ní ìdánilójú pé ẹ̀yin kò sí nínú irú ipò àìnígbàgbọ́ bẹ̃ gẹ́gẹ́bí ti àwọn arákùnrin yín; mo ní ìdánilójú pé ẹ̀yin kò gbé ọkàn yín sókè nínú ìgbéraga, bẹ̃ni, mo níìdánilójú pé ẹ̀yin kò gbé ọkàn an yín lé ọrọ̀ àti ohun asán ayé; bẹ̃ni, mo ní ìdánilójú pé ẹ̀yin kò bọ òrìṣà, ṣùgbọ́n wípé ẹ̀yin nsin Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè, àti pé ẹ̀yin ndúró de ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ títí ayé, èyítí nbọ̀. Nítorí kíyèsĩ, èmi wí fún un yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ni ó nbọ̀wá; kí ẹ kíyèsĩ, ohun kan wà, èyítí ó ṣe pàtàkì ju gbogbo nwọn lọ—nítorí kíyèsĩ, àkokò nã kò jìnà tí Olùràpadà nbọ̀wá tí yíò sí máa gbé ãrín àwọn ènìyàn rẹ̀. Ẹ kíyèsĩ, èmi kò wípé ó nbọ̀wá sí ãrin wa ní àkokò tí ó wà nínú àgọ́ ara; nítorí kí ẹ kíyèsĩ, Ẹ̀mí-Mímọ́ kò tĩ wí fún mi pé báyĩ ni ó rí. Nísisìyí, nípa ohun yíi èmi kò mọ̀; ṣùgbọ́n ohun tí èmi mọ̀ ni èyíi, pé Olúwa Ọlọ́run ní agbára láti ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Ẹ̀mí-Mímọ́ ti sọ èléyĩ fún mi, wípé: Kígbe sí àwọn ènìyàn yíi, wípé—Ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì tún ọ̀nà Olúwa ṣe, kí ẹ sì rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀, èyítí ó gún; nítorí kíyèsĩ, ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀, Ọmọ Ọlọ́run nã sì nbọ̀wá sí orí ilẹ̀ ayé. Sì kíyèsĩ, a o bĩ nípasẹ̀ Màríà, ní Jerúsálẹ́mù èyítí íṣe ilẹ̀ àwọn bàbá nlá wa, òun yíò sì jẹ́ wúndíá, ohun èlò tí ó níye lórí tí a sì yàn, ẹnití a ó ṣíjibò, tí yíò sì lóyún nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, yíò sì bí ọmọkùnrin kan, bẹ̃ni, àní Ọmọ Ọlọ́run. Òun yíò sì jáde lọ, ní ìfaradà ìrora, ìpọ́njú àti àdánwò onírurú; èyítí ó rí bẹ̃ kí ọ̀rọ̀ nã lè ṣẹ, èyítí ó wípé yíò gbé ìrora àti àìsàn àwọn ènìyàn rẹ̀ lé ara rẹ̀. Òun yíò sì gbé ikú lé ara rẹ̀, kí òun kí ó lè já ìdè ikú èyítí ó de àwọn ènìyàn rẹ̀; òun yíò sì gbé gbogbo àìlera wọn lé ara rẹ̀, kí inú rẹ̀ lè kún fún ãnú, nípa ti ara, kí òun kí ó lè mọ̀ nípa ti ara bí òun yíò ṣe ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ nínú gbogbo àìlera wọn. Nísisìyí, Ẹ̀mí-Mímọ́ mọ ohun gbogbo; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Ọmọ Ọlọ́run jìyà nípa ti ara, kí ó lè gbé ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ ka orí ara rẹ̀, kí ó lè pa gbogbo ìwàìrékọjá nwọn rẹ́, nípa agbára ìdásílẹ̀ rẹ̀; àti nísisìyí kíyèsĩ, èyí ni ẹ̀rí èyítí ó wà nínú mi. Nísisìyí mo wí fún yín pé ẹ̀yin níláti ronúpìwàdà, kí ẹ sì di àtúnbí; nítorítí Ẹ̀mí wípé tí ẹ̀yin kò bá di àtúnbí ẹ̀yin kò lè jogún ìjọba ọ̀run; nítorínã ẹ wá kí a sì ṣe ìrìbọmi fún yín sí ìrònúpìwàdà, kí ẹ̀yin lè jẹ́ wíwẹ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀yin lè ní ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀dọ́-Àgùtàn Ọlọ́run nã, ẹni tí ó kó gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ, tí ó tóbi láti gbàlà àti láti wẹ̀mọ́ kúrò nínú gbogbo àìṣòdodo. Bẹ̃ni, èmi wí fún yín ẹ wá ẹ máṣe bẹ̀rù, kí ẹ sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín tì sí apá kan, èyítí ó fi ìrọ̀rùn rọ̀gbàká yín, èyítí ó dè yín mọ́lẹ̀ sí ìparun, bẹ̃ni, ẹ wá, kí ẹ sì kọjá lọ, kí ẹ sì fihàn fún Ọlọ́run yín pé ẹ̀yin ṣetán láti ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì bá a dá májẹ̀mú láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì jẹ́ ẹ̀rí ẹ̀yí sí i lòní nípa wíwọ̀ inú omi ìrìbọmi lọ. Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì ṣe eleyĩ, tí ó sì pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ láti ìsisìyí lọ, òun kannã ni yíò rántí pé èmi wí fún un, bẹ̃ni, òun yíò rántí pé èmi ti wífún un, òun yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí Ẹ̀mí Mímọ́ èyítí ó njẹ́rĩ nínú mi. Àti nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, njẹ́ ẹ̀yin gbà àwọn ohun wọ̀nyí gbọ́? Kíyèsĩ, èmi wí fún un yín, bẹ̃ni, èmi mọ̀ pé ẹ gbà wọ́n gbọ́; ọ̀nà tí èmi sì mọ̀ pé ẹ̀yin gbà wọ́n gbọ́ ni nípa ìṣípayá Ẹ̀mí tí ó wà nínú mi. Àti nísisìyí nítorí ìgbàgbọ́ yín tí ó múná nípa ohun wọnnì, bẹ̃ni, nípa àwọn ohun tí ẹ̀mí sọ, ayọ̀ mí pọ̀ jọjọ. Nítorí bí èmi ṣe wí fún yín láti ìbẹ̀rẹ̀ wá pé èmi ní ìrètí pé ẹ̀yin kò sí ní ipò búburú nnì gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin nyin, bẹ̃ gẹ́gẹ́ èmi ríi pé ìrètí mi ni a ti tẹ́ lọ́rùn. Nítorí èmi ríi pé ẹ̀yin wà ní ipa ọ̀nà òdodo; mo ríi pé ẹ̀yin wà ní ipa ọ̀nà tí ó tọ́ni sí ìjọba Ọlọ́run; bẹ̃ni, èmi ríi pé ẹ̀yin nṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́. Mo ríi pé a ti sọọ́ di mímọ̀ fún yín, nípa ẹ̀rí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun kò lè rìn ní ipa ọ̀na tí ó wọ́; bẹ̃ni kĩ yapa kúrò ní èyítí ó bá ti sọ; bẹ̃ sì ni kò sí àmì ìyípadà kanṣoṣo láti ọ̀tún sí òsì, tàbí láti èyítí ó tọ̀nà sí èyítí ó kùnà; nítorínã, ipa ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ipa ọ̀nà ayérayé kan tí kò yípadà. Òun kĩ sĩ gbé inú tẹ́mpìlì àìmọ́, bẹ̃ sì ni a kò lè gba ohun ẹ̀gbin tàbí ohunkóhun tí kò mọ́ sínú ìjọba Ọlọ́run; nítorínã èmi wí fún un yín pé àkokò nã nbọ̀wá, bẹ̃ni, yíò sì rí bẹ̃ ní ìgbà ìkẹhìn, pé ẹnití ó bá ní ìríra yio wà ní ipò ìríra rẹ̀. Àti nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi sọ àwọn ohun wọ̀nyí fún un yín kí èmi kí ó lè ta yín jí sí ojúṣẽ yín sí Ọlọ́run kí ẹ̀yin lè rìn láìlẹ́bi níwájú rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè rìn ní ẹgbẹ́ mímọ́ ti Ọlọ́run, èyítí a ti gbà yín sí. Àti nísisìyí, èmi rọ̀ yín kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn, kí ẹ sì tẹríba, kí ẹ sì ṣe ìwà-pẹ̀lẹ́; kí ẹ ní ìwà tútù; kí ẹ kún fún ìfaradà àti ìlọ́ra; pẹ̀lú ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ohun gbogbo; sí ìtẹramọ́ pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ní ìgbà gbogbo; ní ìbẽrè ohunkóhun tí ẹ̀yin ṣe aláìní, ní ti ẹ̀mí àti ti ara; kí ẹ sì mã fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nínú ohun gbogbo tí ẹ̀yin bá rí gbà. Kí ẹ̀yin kí ó sì ríi pé ẹ ní ìgbàgbọ́, ìrètí, pẹ̀lú ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, nígbànã ni ẹ̀yin yíò sì lè ṣe iṣẹ́ rere. Kí Olúwa kí ó sì bùkún un yín, kí ó sì pa aṣọ yín mọ́ láìlábàwọ́n, kí ẹ̀yin lè bá Ábráhámù, Ísãkì àti Jákọ́bù jòkó ní ìkẹhìn, pẹ̀lú àwọn wòlĩ mímọ́ tí wọ́n ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé, tí aṣọ yín sì wà ní àìlábàwọ́n, àní gẹ́gẹ́bí aṣọ wọ́n ṣe wà láìlábàwọ́n, ní ìjọba ọ̀run, tí kò sì ní jáde kúrò níbẹ̀ mọ́. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi sọ àwọn ohun wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí Ẹ̀mí-Mímọ́ èyítí ó njẹ́rĩ nínú mi; ẹ̀mí mi sì yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtẹramọ́ pẹ̀lú ìfọkànsìn tí ẹ̀yin ti fi fún ọ̀rọ̀ mi. Àti nísisìyí, njẹ́ kí àlãfíà Ọlọ́run kí ó bà lé yín lórí, àti lórí ilé yín àti ilẹ̀ yín, àti ọ̀wọ́-ẹran, àti agbo-ẹran an yín, àti ohun ìní yín gbogbo, àwọn obìnrin yín àti àwọn ọmọ yín, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ rerẽ yín, láti ìsisìyí lọ, àti títí láéláé. Báyĩ sì ni èmi ti sọ̀rọ̀. Àmin. 8 Álmà nwãsu ó sì nṣe ìrìbọmi ní Mẹ́lẹ́kì—Nwọn kò gbọ́ tirẹ̀ ní Amonáíhà ó sì fi ibẹ̀ sílẹ̀—Ángẹ́lìỌlọ́run kan pàṣẹ fún un kí ó padà síbẹ̀ kí ó sì kéde ìrònúpìwàdà sí àwọn ènìyàn nã—Ámúlẹ́kì gbã, àwọn méjẽjì sì nwãsù ní Amonáíhà. Ní ìwọ̀n ọdún 82 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ó sì ṣe tí Álmà padà bọ̀ láti ilẹ̀ Gídéónì, lẹ́hìn tí ó ti kọ́ àwọn ará Gídéónì ní ohun púpọ̀ tí a kò lè kọ sílẹ̀, tí ó sì ti da ipa-ọ̀nà ti ìjọ nã sílẹ̀, gẹ́gẹ́bí ó ti ṣe síwájú ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, bẹ̃ni, ó padà sí ilé rẹ̀ ní Sarahẹ́múlà láti fún ara rẹ̀ ní ìsinmi lẹ́hìn lãlã tí ó ti ṣe. Báyĩ sì ni ọdún kẹẹ̀sán parí nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì. Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹẹ̀wá ní ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, tí Álmà jáde lọ kúrò níbẹ̀, tí ó sì mú ìrìnàjò pọ̀n lọ sí ilẹ̀ Mẹ́lẹ́kì, ní ìhà ìwọ̀-oòrùn odò Sídónì, ní apá ìwọ̀-oòrùn, ní etí aginjù. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sĩ kọ́ àwọn ènìyàn nã ní ilẹ̀ Mẹ́lẹ́kì gẹ́gẹ́bí ẹgbẹ́ mímọ́ nã ti Ọlọ́run, èyítí a fi pẽ; ó sì bẹ̀rẹ̀sí kọ́ àwọn ènìyàn nã jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ Mẹ́lẹ́kì. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã tọ̣́ wá jákè-jádò ìhà etí ilẹ̀ nã èyítí ó wà ní ìhà aginjù. A sì rì nwọn bọmi jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã; Nígbàtí ó sì ti parí iṣẹ́ rẹ̀ ní Mẹ́lẹ́kì, ó jáde kúrò níbẹ̀, ó sì rin ìrìn-àjò ọjọ́ mẹ́ta lọ sí apá àríwá ilẹ̀ Mẹ́lẹ́kì; ó sì dé ìlú-nlá kan tí à npè ní Amonáíhà. Nísisìyí, ó jẹ́ àṣà àwọn ará Nífáì láti pe ilẹ̀ wọn, àti ìlú-nlá wọn, àti ìletò wọn, bẹ̃ni, àní gbogbo ìletò kékèké wọn, ní orúkọ ẹnití ó kọ́kọ́ tẹ̀ nwọ́n dó; báyĩ sì ni ó rí ní ti ilẹ̀ Amonáíhà. Ó sì ṣe, nígbàtí Álmà ti dé ìlú-nlá Amonáíhà ó bẹ̀rẹ̀ sĩ wãsu ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn. Nísisìyí, Sátánì ti gba ọkàn àwọn ará ìlú-nlá Amonáíhà; nítorínã, wọn kò tẹ́tísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ Álmà. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Álmà ṣe lãlã nínú ẹ̀mí, tí ó sì nbá Ọlọ́run ja ìjàkadì nínú ọ̀pọ̀ àdúrà, pé kí ó lè da Ẹ̀mí rẹ̀ lé orí àwọn ènìyàn nã tí wọ́n wà ní ìlú-nlá nã; kí òun kí ó lè ṣe ìrìbọmi fún nwọn sí ti ìrònúpìwàdà. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, wọ́n sé ọkàn nwọn le, nwọ́n sì wí fún un pé: Kíyèsĩ, àwa mọ̀ wípé Álmà ni ìwọ íṣe; àwa sì mọ̀ pé ìwọ ni olórí àlùfã lórí ìjọ èyítí ìwọ ti dá sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè ilẹ̀ yíi, gẹ́gẹ́bí àṣà rẹ; àwa kĩ ṣe ti ìjọ rẹ, àwa kò sì gba iru àwọn àṣà aṣiwèrè wọnnì gbọ́. Àti nísisìyí, àwa mọ̀ wípé nítorípé àwa kĩ ṣe ti ìjọ rẹ, àwa mọ̀ wípé ìwọ kò ní agbára lórí wa; ìwọ sì ti gbé ìtẹ́ ìdájọ́ lé Néfáíhà lọ́wọ́; nítorínã ìwọ kĩ ṣe adájọ́-àgbà lórí wa. Nísisìyí nígbàtí àwọn ènìyàn wọ̀nyí sì ti wí báyĩ tán, tí wọ́n sì ta ko gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí nwọ́n sì pẹ̀gàn rẹ̀, tí wọ́n tutọ́ síi lára, tí wọ́n sì lée jáde kúrò nínú ìlú wọn, ó kúrò níbẹ̀, ó sì mú ìrìn-àjò rẹ̀ lọ sí ìhà ìlú-nlá èyítí à npè ní Áárọ́nì. Ó sì ṣe, nígbàtí ó nrin ìrìn-àjò lọ síbẹ̀, bí ó ti jẹ́ pé ìbànújẹ́ wọ̣́lọ́rùn, tí ó sì nlọ pẹ̀lú ìpọ́njú àti ìrora ọkàn, nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìlú-nlá Amonáíhà, ó sì ṣe, bí Álmà sì ti ṣe kún fún ìbànújẹ́, wọ́, ángẹ́lì Ọlọ́run kan yọ síi, tí ó wípé: Alábùkún-fún ni ìwọ, Álmà; nítorínã, gbé orí rẹ sókè kí o sì yọ̀, nítorítí ìwọ ní ìdí pàtàkì láti yọ̀; nítorítí ìwọ ti jẹ́ olódodo nípa pipa awọn òfin Ọlọ́run mọ́, láti ìgbàtí ìwọ ti kọ́kọ́ gba ọ̀rọ̀ láti ọwọ́ rẹ̀. Kíyèsĩ, èmi ni ẹnití ó fíi fún ọ. Sì kíyèsĩ, a rán mi láti pàṣẹ fún ọ pé kí o padà lọ sí ìlú-nlá Amonáíhà, kí o sì tún wãsù sí àwọn ènìyàn ìlú nã; bẹ̃ni, kí o wãsù sí nwọn. Bẹ̃ni, wí fún wọn, bí wọn kò bá ronúpìwàdà Olúwa Ọlọ́run yíò pa wọ́n run. Nítorí kíyèsĩ, ní àkokò yí, wọ́n gbìmọ̀ láti pa òmìnira àwọn ènìyàn rẹ run, (nítorí báyĩ ni Olúwa wí) èyí tí ó sì lòdì sí ìlànà, ìdájọ́ àti òfin, èyítí ó ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí Álmà ti gba iṣẹ́ yíi láti ọwọ́ ángẹ́lì Olúwa, ó padà kánkán lọ sí ilẹ̀ Amonáíhà. Ó sì bá ọ̀nà míràn wọ inú ìlú-nlá nã, bẹ̃ni, ọ̀nà èyítí ó wà ní ìhà gúsù ìlú-nlá Amonáíhà. Bí ó sì ti wọ ìlú-nlá nã, ebi npã, òun sì wí fún ọkùnrin kan pé: Njẹ́ ìwọ lè fún onírẹ̀lẹ̀ọkàn ìránṣẹ́-Ọlọ́run ní ohun tí yíò jẹ́? Ọkùnrin nã sì wí fún un: Ará Nífáì ni èmi, èmi sì mọ̀ wípé wòlĩ mímọ́ Ọlọ́run ni ìwọ íṣe, nítorí ìwọ ni ẹni nã tí ángẹ́lì wí nínú ìran pé: Ìwọ yíò gbã. Nítorínã, tẹ̀lé mi lọ sí ilé mi èmi yíò sì fún ọ nínú oúnjẹ mi; èmi sì mọ̀ wípé ìwọ yíò jẹ́ ìbùkún fún èmi àti ilé mi. Ó sì ṣe tí ọkùnrin nã gbã sí ilé rẹ̀; ọkùnrin nã sì ni à npè Ámúlẹ́kì; òun sì mú oúnjẹ jáde wá pẹ̀lú ẹran, ó sì gbé wọn sí iwájú Álmà. Ó sì ṣe tí Álmà jẹ oúnjẹ, ó sì yó; ó sì súre fún Ámúlẹ́kì àti ilé rẹ, ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run. Lẹ́hìn tí ó sì ti jẹun tí ó si yo; ó wí fún Ámúlẹ́kì: Èmi ni Álmà, èmi sì ni olórí àlùfã lórí ìjọ Ọlọ́run jákè-jádò ilẹ̀ nã. Sì kíyèsĩ, a ti pè mí láti wãsu ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lãrín àwọn ènìyàn yíi gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ìfihàn àti ìsọtẹ́lẹ̀; èmi sì wà ní ilẹ̀ yíi, wọ́n kò gbà mí, ṣùgbọ́n wọ́n lé mí síta, èmi sì ti ṣetán láti kẹ̀hìn sí ilẹ̀ yíi títí láéláé. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, a ti pã láṣẹ fún mi kí èmi kí ó tún padà, kí èmi sì sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn yíi, bẹ̃ni, kí èmi sì jẹ́ ẹ̀rí sí wọn nípa àìṣedẽdé nwọn. Àti nísisìyí, Ámúlẹ́kì, nítorítí ìwọ fún mi ní oúnjẹ tí ìwọ sì gbà mi wọlé, ìbùkún ni fún ọ; nítorípé ebi ti pa mí, nítorítí èmi ti ngbãwẹ̀ fún ọjọ́ púpọ̀. Álmà sì dúró fún ọjọ́ púpọ̀ pẹ̀lú Ámúlẹ́kì kí ó tó bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí àwọn ènìyàn nã. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã tẹra mọ́ ìwà búburú ṣíṣe lọ́pọ̀lọpọ̀. Ọ̀rọ̀ nã sì tọ Álmà wá, wípé: Lọ; kí o sì wí fún ìránṣẹ́ mi Ámúlẹ́kì, jáde lọ kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn yíi, wípé—Ẹ ronúpìwàdà, nítorípé báyĩ ni Olúwa wí, tí ẹ̀yin kò bá ronúpìwàdà èmi yíò bẹ àwọn ènìyànyí wò nínú ìbínú mi, bẹ̃ni, èmi kò sì ní ká ìbínú mi kúrò. Álmà sì jáde lọ, àti Ámúlẹ́kì pẹ̀lú, lãrín àwọn ènìyàn nã, láti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí wọn; wọ́n sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. A sì fún nwọn ní agbára, tó bẹ̃ tí wọn kò rí wọn dè mọ́lẹ̀ nínú túbú; kò sì ṣeéṣe kí ẹnìkẹ́ni lè pa wọ́n; bíótilẹ̀ríbẹ̃, wọn kò lo agbára wọn, àfi ìgbà tí wọ́n dè wọ́n ní ìdè, tí nwọ́n sì jù wọ́n sínú túbú. Nísisìyí, a ṣe eleyĩ, kí Olúwa bá lè fi agbára rẹ̀ hàn nínú wọn. Ó sì ṣe tí wọ́n jáde lọ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sĩ wãsù tí wọ́n sì nsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn nã gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí àti agbára èyítí Olúwa ti fifún nwọn. Àwọn ọ̀rọ̀ Álmà, àti àwọn ọ̀rọ̀ Ámúlẹ́kì pẹ̀lú, èyítí a kéde sí àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Amonáíhà. Àti pẹ̀lú pé a gbé wọn jù sínú túbú, a sì kó wọn yọ nípa ìyanu agbára Ọlọ́run èyítí ó wà nínú wọn, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ti Álmà. Èyítí a kọ sí àwọn orí 9 títí ó fi dé 14 ní àkópọ̀. 9 Álmà pàṣẹ fún àwọn ará Amonáíhà pé kí nwọ́n ronúpìwàdà—Olúwa yíò ṣãnú fún àwọn ará Lámánì ní ọjọ́ ìkẹhìn—Tí àwọn ará Nífáì bá kọ ìmọ́lẹ̀ nã sílẹ̀, a ó pa wọ́n run láti ọwọ́ àwọn ará Lámánì—Ọmọ Ọlọ́run nã fẹ́rẹ̀ dé—Òun yíò ṣe ìràpadà fún àwọn tí ó ronúpìwàdà padà, tí a ṣe ìrìbọmi fún, tí wọn sì ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 82 kí a tó bí Olúwa wa. Àti pẹ̀lú, èmi, Álmà, nítorítí Ọlọ́run ti pã láṣẹ pé kí èmi kí ó mú Ámúlẹ́kì kí a sì tún kọjá lọ wãsù sí àwọn ènìyàn yí, àní àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ìlú-nlá Amonáíhà, ó sì ṣe, bí èmi ṣe bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí nwọn, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀sí jà mí níyàn, pé: Tani ìwọ íṣe? Njẹ́ ìwọ ha rò pé àwa yíò gba ẹ̀rí ẹnìkan gbọ́, bí òun tilẹ̀ wãsù sí wa pé ayé yíò rékọjá? Nísisìyí, ọ̀rọ̀ tí wọn nsọ kò yé wọn; nítorítí wọn kò mọ̀ wípé ayé yíò rékọjá. Nwọ́n sì tún wípé: Àwa kò lè gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́ bí ìwọ tilẹ̀ sọtẹ́lẹ̀ pé ìlú-nlá yíi yíò pàrùn ní ọjọ́ kan. Nísisìyí, wọn kò mọ̀ pé Ọlọ́run lè ṣe iṣẹ́ nlá irú èyí, nítorítí nwọ́n jẹ́ ọlọ́kàn-líle àti ọlọ́rùn-líle ènìyàn. Nwọ́n sì wí pé: tani Ọlọ́run, tí kò rán ju ẹnìkan pẹ̀lú àṣẹ lãrín àwọn ènìyàn yí, láti kéde fún wọn nípa òtítọ́ tí ó wà nínú àwọn ohun nlá àti ohun ìyàlẹ́nu yĩ. Nwọ́n sì dìde láti gbé ọwọ́ wọn lé mi; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, wọn kò sì ṣe eleyĩ. Èmi sì dúró pẹ̀lú ìgboyà láti wí fún wọn pé, bẹ̃ni, èmi jẹ́ ẹ̀rí pẹ̀lú ìgboyà fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ, A! ẹ̀yin ìran búburú àti aláìgbọràn ènìyàn yì, báwo ni ẹ̀yin ṣe ti gbàgbé àṣà àwọn bàbá yín; bẹ̃ni, báwo ni ẹ̀yin ṣe ti gbàgbé awọn òfin Ọlọ́run ní kánkán. Njẹ́ ẹ̀yin kò ha rántí pé bàbá wa Léhì, ni a mú jáde kúrònínú Jerúsálẹ́mù nípa ọwọ́ agbára Ọlọ́run? Njẹ́ ẹ̀yin kò ha rántí pé gbogbo wọn ni ó mú la aginjù kọjá? Njẹ́ ẹ̀yin ti gbàbgé ní kánkán àwọn ìgbà tí ó gba àwọn bàbá wa lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí ó sì pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ìparun, àní láti ọwọ́ àwọn arákùnrin wọn? Bẹ̃ni, tí kò bá sí ti agbára rẹ̀ aláìláfiwé, àti ãnú rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ sũrù sí wa, láìlèyẹ̀ kúrò àwa kì bá ti di kíké kúrò lórí ilẹ̀ ayé ní àtẹ̀hìnwá ṣãjú àkokò yí, ati bóyá tí a ó sì ti kọ̀ wá sí ipò ìbànújẹ́ àti ègbé tí kò nípẹ̀kun. Ẹ kíyèsĩ, nísisìyí mo wí fún un yín pé ó pã láṣẹ pé kí ẹ ronúpìwàdà; tí ẹ̀yin kò bá sì ronúpìwàdà, ẹ̀yin kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run rárá. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èyí nìkan kọ́—òun ti pã láṣẹ pé kí ẹ ronúpìwàdà, bíkòjẹ́ bẹ̃ òun yíò pa yín run pátápátá kúrò lórí ilẹ̀ ayé; bẹ̃ ni, òun yíò bẹ̀ yín wo nínú ìbínú rẹ̀, òun kò sì ní ká ìbínú rẹ̀ èyítí ó pọ̀ jọjọ kúrò. Ẹ kíyèsĩ, njẹ́ ẹ̀yin kò ha rántí àwọn ọ̀rọ̀ èyítí ó sọ fún Léhì, tí ó wípé: Níwọ̀n ìgbàtí ẹ̀yin bá pa òfin mi mọ́, ẹ̀yin yíò ṣe rere lórí ilẹ̀ nã? Àti pẹ̀lú a tún wípé: Níwọ̀n ìgbàtí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́, a o ké yín kúrò níwájú Olúwa. Nísisìyí, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí, pé níwọ̀n ìgbàtí àwọn ará Lámánì kò pa òfin Ọlọ́run mọ́, a ké wọn kúrò níwájú Olúwa. Nísisìyí àwa ríi pé ọ̀rọ̀ Olúwa ti ṣẹ nípa ohun yĩ, a sì ti ké àwọn Lámánì kúrò níwájú rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ìwàìrékọjá wọn ní ilẹ̀ nã. Bíótilẹ̀ríbẹ̃ mo wí fún yín, wípé yíò sàn fún wọn ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín lọ, tí ẹ̀yin bá dúró nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀ yín, bẹ̃ni, yíò sì rọrùn fún wọn nínú ayé yĩ jù fún yín lọ, àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà. Nítorípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlérí ni a ṣe fún àwọn ará Lámánì; nítorípé nípa àṣà àwọn bàbá wọn ni wọ́n ṣe wà ní ipò àìmọ̀; nítorínã Olúwa yíò ṣãnú fún wọn yíò sì mú kí ìgbà wọn pẹ́ ní órí ilẹ̀ nã. Àti pé ní àkokò kan a ó mú wọn wá sí gbígba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́ àti lati mọ àìpé àṣà bàbá wọn; ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni a ó sì gbàlà, nítorípé Olúwa yíò ṣãnú gbogbo àwọn tí ó pa orúkọ rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún yín pé bí ẹ̀yin bá tẹramọ́ ṣíṣe ìwà búburú yín, pé ọjọ́ yín kì yíò pẹ́ ní orí ilẹ̀ nã, nítorítí a ó rán àwọn ará Lámánì láti kọlũ yín; tí ẹ̀yin kò bá sì ronúpìwàdà, wọn yíò wá ní àkokò tí ẹ̀yin kò mọ̀, a ó sì fi ìparun pátápátá bẹ̀ yín wò; yíò sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbóná ìbínú Olúwa. Nítorítí òun kò ní gbà fún un yín pé kí ẹ̀yin kí ó wà nínú ìwà búburú yín, láti pa àwọn ènìyàn rẹ̀ run. Èmi wí fún un yín, Rárá; ó sàn fún kí ó gbà fún àwọn ará Lámánì láti pa gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ tí à npè ní ará Nífáì run, tí ó bá ṣeéṣe kí wọ́n ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá, lẹ́hìn tí Olúwa Ọlọ́run wọn ti fún nwọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ́lẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀; Bẹ̃ni, lẹ́hìntí wọ́n ti jẹ́ ẹni-àyànfẹ́ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀rí; bẹ̃ni, lẹ́hìn tí a ti fẹ́ràn wọn ju gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, ahọ́n, tàbí ènìyàn; lẹ́hìntí a ti fi ohun gbogbo hàn nwọ́n, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú wọn, àti ìgbàgbọ́ wọn, àti àdúrà,èyítí ó ti kọjá lọ, èyítí ó nbẹ, àti èyítí ó nbọ̀wá; Tí a sì ti bẹ̀ wọ́n wò nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run; tí wọ́n ti bá àwọn ángẹ́lì sọ̀rọ̀, tí a sì ti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohùn Olúwa; tí nwọ́n sì ní ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀; àti ẹ̀mí ìfihàn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn, ẹ̀bùn fífi èdè sọ̀rọ̀, àti ẹ̀bùn ìwãsù, àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, àti ẹ̀bùn ìtumọ̀ èdè; Bẹ̃ni, lẹ́hìn tí Ọlọ́run sì ti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, nípa agbára Olúwa; tí a ti kó wọn yọ kúrò nínú ìyàn, àti àìsàn, àti onírurú àrùn lóríṣiríṣi; tí wọn sì ti di alágbára ní ogun, kí wọ́n má lè pa wọ́n run; tí a sì ti mú wọn kúrò nínú oko-ẹrú láti ìgbà dé ìgbà, tí a sì ti pa wọ́n mọ́ títí di àkokò yí; wọ́n sì ti ṣe rere, títí wọ́n fi di ọlọ́rọ̀ nínú onírũrú ohun— Àti nísisìyí ẹ kíyèsí, mo wí fún un yín, pé tí àwọn ènìyàn yí tí wọ́n ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún gbà láti ọwọ́ Olúwa, bá rékọjá ní ìlòdì sí ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀ èyítí wọ́n ní, èmi wí fún yín pé tí ó bá rí báyĩ, pé tí wọ́n bá ṣubú sínú ìrékọjá, yíò sàn fún àwọn ará Lámánì jù fún wọn lọ. Nítorí kíyèsí, ìlérí Olúwa tàn dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Lámánì, ṣùgbọ́n kò dé ọ̀dọ̀ yín bí ẹ̀yin bá rékọjá; nítorípé, njẹ́ Olúwa kò ha ṣèlérí tí ó sì ṣe òfin èyítí ó múlẹ̀ pé bí ẹ̀yin bá ṣe ọ̀tẹ̀ sí òun, a ó pa yín run pátápátá kúrò lórí ilẹ̀ ayé yĩ? Àti nísisìyí, nítorí ìdí èyí, kí ẹ̀yin kí ó má bã parun, Olúwa ti rán àwọn ángẹ́lì rẹ̀ láti bẹ ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò, tí ó wí fún wọn pé wọ́n níláti jáde lọ kí wọ́n sì kígbe sí àwọn ènìyàn yí pé: Ẹ ronúpìwàdà, nítorítí ìjọba ọ̀run fẹ̃ dé; Láìpẹ́ ọjọ́ sí àkokò yí, Ọmọ Ọlọ́run yíò wá ní ògo rẹ̀; ògo rẹ̀ yíò sì jẹ́ ògo ti Ọmọ bíbí ti Bàbá nìkanṣoṣo, tí ó kún fún ọ́re-ọ̀fẹ́, ìṣòtítọ́; àti òtítọ́, ó kún fún sũrù, ãnú, ọ̀pọ̀-sũrù, ó sì ṣe kánkán láti gbọ́ igbe àwọn ènìyàn rẹ̀ àti láti gbọ́ àdúrà wọn. Ẹ kíyèsĩ, ó nbọ̀wá láti ra àwọn tí ó ṣe ìrìbọmi sí ìrònúpìwàdà padà, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀. Nítorínã, ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe; nítorítí àkokò nã ti dé tán tí gbogbo ènìyàn yíò kórè iṣẹ́ nwọn, gẹ́gẹ́bí èyí tí nwọ́n ti jẹ́—bí nwọ́n bá ti jẹ́ olódodo nwọn yíò kórè ìgbàlà ọkàn nwọn, nípa agbára àti ìdásílẹ̀ Jésù Krístì; bí nwọ́n bá sì ti jẹ́ búburú, nwọn yio kórè ìdálẹ́bi àìnípẹ̀kun ọkàn nwọn, gẹ́gẹ́bí agbára àti ìfinisí ìgbèkùn ti èṣù. Nísisìyí kíyèsĩ, èyí ni ohùn ángẹ́lì, tí ó nké pe àwọn ènìyàn. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, nítorí arákùnrin mi ni ẹ̀yin íṣe, ó sì tọ́ kí ẹ̀yin jẹ́ àyànfẹ́, ó sì tọ́ kí ẹ̀yin ṣe iṣẹ́ èyítí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, nítorípé ọkàn an yín ti le púpọ̀ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorípé ẹ̀yin jẹ́ ènìyàn ti o ti sọnu tí ó sì ti ṣubú. Nísisìyí ó sì ṣe, pe nígbàtí èmi, Álmà, tí sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kíyèsí, inú bí àwọn ènìyàn nã sí mi nítorípé èmi sọ fún wọn pé ọlọ́kàn-líle àti ọlọ́rùnlíle ènìyàn ní wọ́n íṣe. Àti pẹ̀lú pé nítorítí èmi wí fún wọn pé wọn ti di ẹni-sísọnù àti ẹni ìṣubú ènìyàn wọ́n bínú sí mi, wọ́n sì wá ọ̀nà láti gbéọwọ́ wọn lé mi, pé kí wọ́n lè gbé mi jù sínú túbú. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí Olúwa kò gbà fún wọn pé kí wọ́n mú mi ní ìgbà nã kí wọ́n sì gbé mi jù sínú túbú. Ó sì ṣe tí Ámúlẹ́kì lọ tí ó sì dúró, síbẹ̀ o si bẹ̀rẹ̀ sí wãsù sí wọn pẹ̀lú. Àti nísisìyí a kò kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Ámúlẹ́kì, bíótilẹ̀ríbẹ̃, nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé yĩ. 10 Léhì jẹ́ ìran Mánássè—Ámúlẹ́kì tún sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ tí ángẹ́lì fún un pé kí ó tọ́jú Álmà—Àdúrà àwọn olódodo-ènìyàn ngba àwọn ènìyàn là—Àwọn aláìṣọ́tọ́ amòfin àti adájọ́ ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìparun àwọn ènìyàn. Ní ìwọ̀n ọdún 82 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí Ámúlẹ́kì wãsù sí àwọn ènìyàn tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Amonáíhà, wípé: Èmi ni Ámúlẹ́kì; ọmọ Gídónà ni èmi íṣe, ẹnití íṣe ọmọ Íṣmáẹ́lì, tĩ sì íṣe àtẹ̀lé Ámínádì; Ámínádì kannã sì ni ó túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ sí ára ògiri tẹ́mpìlì, èyítí a kọ nípa ìka Ọlọ́run. Ámínádì sì jẹ́ ìran Nífáì, ẹnití íṣe ọmọ Léhì, èyítí ó jáde kúrò láti inú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, ẹnití íṣe ìran Mánássè, ẹnití íṣe ọmọ Jósẹ́fù, ẹnití a tà sí ilẹ̀ Égíptì láti ọwọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀. Ẹ kíyèsĩ, èmi jẹ́ ẹni tí o ní orúkọ rere pẹ̀lú lãrín àwọn tí ó mọ̀ mí; bẹ̃ni, ẹ sì kíyèsĩ, èmi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbátan àti ọ̀rẹ́, èmi sì ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ nípa iṣẹ́ ọ́gùn ojú mi. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, lẹ́hìn gbogbo èyí, èmi kò mọ́ púpọ̀ nínú àwọn ọ̀nà Olúwa, àti ohun ìjìnlẹ̀ rẹ̀, àti agbára nlá rẹ̀. Mo wípé èmi kò mọ́ púpọ̀ nínú àwọn ohun wọ̀nyí tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ èmi kùnà, nítorítí mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ rẹ̀ àti agbára nlá rẹ̀; bẹ̃ni, àní nínú ìpamọ́ ìgbésí ayé àwọn ènìyàn yĩ. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo se àyà mi le, nítorí tí a pè mí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, èmi sì ṣe àìgbọ́; nítorínã èmi mọ̀ nípa àwọn ohun wọ̀nyí, síbẹ̀ èmi sì ṣe àìmọ̀; nítorínã èmi tẹ̀ síwájú nínú ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run nínú ìwà búburú ọkàn mi, àní títí di ọjọ́ kẹ́rin nínú oṣù kéje yĩ, èyítí ó wà nínú ọdún kẹẹ̀wá ti ìjọba àwọn onídàjọ́. Bí èmi sì ṣe nrin ìrìnàjò lọ sí ọ̀dọ̀ ìbátan tí ó súnmọ́ mi kan, kíyèsĩ, ángẹ́lì Olúwa farahàn mí ó sì wípé: Ámúlẹ́kì, padà sí ilé rẹ, nítorítí ìwọ yíò bọ́ wòlĩ Olúwa; bẹ̃ni, ẹni mímọ́ kan, ènítí íṣe ẹnití Ọlọ́run yàn; nítorítí ó ti gba ãwẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yí, ebi sì npa á, ìwọ yíò sì gbã sínú ilé rẹ, ìwọ yíò bọ́ọ, òun yíò sì bùkún fún ọ pẹ̀lú ilé rẹ; ìbùkún Olúwa yíò sì wà lórí rẹ àti ilẽ rẹ. Ó sì ṣe tí èmi gbọ́ran sí ohùn ángẹ́lì nã, èmi sì padà lọ sí ilé mi. Bí èmi sì ṣe nlọ sí ibẹ̀, èmi rí ọkùnrin nã èyítí ángẹ́lì sọ fún mi pé: Ìwọ yio gbà sínú ilé rẹ—sì kíyèsĩ ọkùnrin yìi kan nã ní ó ti nbá a yín sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun Ọlọ́run. Ángẹ́lì nã sì wí fún mi pé ẹni-mímọ́ ni íṣe; nítorí-eyi èmi mọ̀ pé ẹni-mímọ́ ni íṣe nítorípé ángẹ́lì Ọlọ́run ti wí bẹ̃. Àti pẹ̀lú, èmi mọ̀ pé àwọn ohun tí ó ti jẹri sì jẹ́ òtítọ́; nítorí kíyèsĩ èmi wí fún yín, pé bí Olúwa ti wà lãyè, bẹ̃ nã ni ó ṣe rán ángẹ́lì rẹ̀ láti fi àwọn ohun wọ̀nyí hàn mí; ó sì ti ṣe èyí ní àkokò tí Álmà yĩ gbé inú ilé mi. Nítorí ẹ kíyèsĩ, òun ti bùkún fún ilé mi, ó ti bùkún fún mi, àti àwọn obìnrin mi, àti àwọn ọmọ mi, àti bàbá mi, àti àwọn ìbátan mi; bẹ̃ni, àní gbogbo tẹbítará mi ni ó bùkún fún, tí ìbùkún Olúwa sì ti wà lórí gbogbo wa gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ. Àti nísisìyí, nígbàtí Ámúlẹ́kì ti sọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ẹnu bẹ̀rẹ̀sí ya àwọn ènìyàn nã, ní rírí tí wọ́n ríi pé ojú ẹlẹ̃rí ẹyọ kan tí ó jẹ́rĩ sí ohun ti a fi sùn nwọ́n, àti pẹ̀lú nípa àwọn ohun èyítí nbọ̀wá gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú nwọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn kan wà lãrín wọn tí wọ́n gbèrò láti ṣe ìwãdí ọ̀rọ̀ lẹ́nu wọn, pé nípa ọ̀nà àrékérekè wọn, wọn ò rí wọn mú nípa ọ̀rọ̀ tí wọn yíò sọ, pé wọn yíò rí ẹlẹ̃rí tí yíò ta kò wọ́n, tí wọn yíò sì fi wọ́n lé àwọn adájọ́ nwọn lọ́wọ́, tí nwọn yíò sì ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́bí òfin, tí wọn yíò sì pa wọ́n tàbí kí wọ́n jù wọ́n sínú túbú, gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n yíò fi sùn wọ́n. Nísisìyí àwọn ọkùnrin wọnnì ni wọ́n wá ọ̀nà láti pa nwọ́n run, tí nwọ́n jẹ́ agbẹjọ́rò, tí nwọ́n gbà, tàbí tí àwọn ènìyàn nã yàn láti gbé òfin ró ní ìgbà ìpèlẹ́jọ́ nwọn, tàbí ní àkokò ìpèlẹ́jọ́ ní iwájú adájọ́ fún ìwà arúfin tí àwọn ènìyàn bá hù. Nísisìyí, àwọn agbẹjọ́rò wọ̀nyí ní ìmọ̀ ní gbogbo ọ̀nà ọgbọ́n àrekérekè àwọn ènìyàn nã; ìdí èyí sì ni kí nwọ́n lè já fáfá nínú iṣẹ́ nwọn. Ó sì ṣe tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí bí Ámúlẹ́kì lọ́rọ̀, ní ọ̀nà tí òun yíò fi tako ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, tàbí kí ó lọ́ ẹjọ́ mọ́ ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀ nípa ohun tí yíò sọ. Nísisìyí nwọn kò mọ̀ pé Ámúlẹ́kì lè mọ̀ nípa ète nwọn. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí bĩ lẹ́jọ́, ó mọ́ èrò ọkàn nwọn, ó sì sọ fún nwọn pé: Á!, ẹ̀yin ìran aláìgbàgbọ́ àti alárèkérekè ènìyàn yí, ẹ̀yin agbẹjọ́rò àti àgàbàgebè ènìyàn, nítorítí ẹ̀yin nfi ìdí èṣù mulẹ̀; nítorítí ẹ̀yin ndọdẹ sílẹ̀ àti ìkẹ́kùn láti mú àwọn ẹni mímọ́ Ọlọ́run. Ẹ̀yin ngbèrò làti yí àwọn ọ̀nà òdodo padà, àtí láti mú ìbínú Ọlọ́run sọ̀ kalẹ̀ wá sí óríi yín, àní títí dé ìparun àwọn ènìyàn yí. Bẹ̃ni, Mòsíà ti sọọ́ dáradára, ẹnití íṣe ọba wa tí ó kẹ́hìn, nígbàtí ó ṣetán láti gbé ìjọba sílẹ̀, tí kò sì sí ẹnití yíò gbée lé lọ́wọ́, èyítí ó sì jẹ́ kí ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ pé kí nwọ́n ṣe ìjọba nwọn nípa ohùn ara nwọn—bẹ̃ni, ó sì sọọ́ dáradára pé tí àkokò nã bá dé tí ohùn àwọn ènìyàn yí bá yan ìwà búburú, èyí ni pé, tí àkokò nã bá dé tí àwọn ènìyàn bá ṣubú sínú ìwàìrékọjá, nwọ́n ti ṣetán fún ìparun. Àti nísisìyí, èmi wí fún un yín pé Olúwa nṣe ìdájọ́ àìṣedẽdé yín; ó nkígbe pe àwọn ènìyàn yí, nípa ohùn àwọn ángẹ́lì rẹ: Ẹ ronúpìwàdà, ronúpìwàdà, nítorítí ìjọba ọ̀run ti dé tán. Bẹ̃ni, ó nkígbe, nípa ohùn àwọn ángẹ́lì rẹ pé: Èmi nsọ̀kalẹ̀bọ̀wá sí ãrin àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú ìṣòtítọ́ àti àìṣègbè ní ọwọ́ mi. Bẹ̃ni, èmi wí fún yín pé tí kò bá jẹ́ ti àdúrà àwọn olódodo tí nwọ́n wà nínú ilẹ̀ yí, pé à bá ti bẹ̀ yín wò pẹ̀lú ìparun nlá; síbẹ̀ kò ní ṣe nípa ìkún-omi, gẹ́gẹ́bí ti àwọn wọnnì ní ìgbà Nóà, ṣùgbọ́n yíò jẹ́ nípa ìyàn, àti nípa àjàkálẹ̀-àrùn, àti idà. Ṣùgbọ́n, nípa àdúrà àwọn olódodo ni a fi dáa yín sí; nítorínã, bí ẹ̀yin bá ta olódodo nã nù lãrín yín, nígbàyí ni Olúwa kò ní dá ọwọ́ rẹ dúró; ṣùgbọ́n nínú híhó ìbínú rẹ ni yíò jáde wá kọlũ yí; ni a ó sì fi ìyàn bã yín jà, àti àjàkálẹ̀-àrùn, àti idà; ìgbà nã sì ti dé tán, àfi tí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã túbọ̀ bínú sí Ámúlẹ́kì síi, tí nwọ́n sì kígbe sókè wìpé: Ọkùnrin yĩ ni ó ntako òfin wa èyítí ó tọ́, àti àwọn ọlọgbọ́n agbẹjọ́rò wa tí àwa ti yàn. Ṣùgbọ́n Ámúlẹ́kì na ọwọ́ rẹ síwájú, ó sì tún kígbe sí nwọn ju ti àtẹ̀hìnwá lọ, wípé: Á!, ẹ̀yin ìran búburú àti alárèkérekè ènìyàn, kíni ìdíi rẹ̀ tí Sátánì ṣe rí ọkàn an yín gbà tó báyĩ? Kíni ìdí rẹ tí ẹ̀yin yíò jọ̀wọ́ ara yín fún un tí òun yíò ní agbára lórí yín láti fọ́ lójú, tí ọ̀rọ̀ tí àwa nsọ yí kò lè yé yín, gẹ́gẹ́bí òdodo wọn? Nítorí kíyèsĩ, njẹ́ èmi jẹ́rĩ tako òfin yín? Kò yé yín; ẹ̀yin wípé èmi sọ̀rọ̀ tako òfin yín; ṣùgbọ́n èmi kò ṣe bẹ̃, ṣùgbọ́n èmi sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òfin yín, sí ìdálẹ́bi yín. Àti nísisìyí, èmi wí fún un yín, pé ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìparun àwọn ènìyàn yí ti bẹ̀rẹ̀sí di ìfilọ́lẹ̀ nípasẹ̀ àìṣòdodo àwọn agbẹjọ́rò yín àti àwọn onídàjọ́ yín. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Ámúlẹ́kì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn nã kígbe takọ́, wípé: Àti nísisìyí àwa mọ̀ wípé ọmọ èṣù ni ọkùnrin yĩ íṣe, nítorípé ó ti purọ́ fún wa; nítorítí ó sọ̀rọ̀ tako òfin wa. Nísisìyí òun sì wípé òun kò sọ̀rọ̀ takọ́. Àti pẹ̀lú, òun ti kẹ́gàn àwọn agbẹjọ́rò wa, àti àwọn onídàjọ́ wa. Ó sì ṣe tí àwọn agbẹjọ́rò nã tẹ ọ̀rọ̀ yí mọ́ ọkàn nwọn, pé kí wọ́n ó lè rántí àwọn ohun wọ̀nyí láti fi takọ́. Ẹnìkan sì wà lãrín nwọn tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Sísrọ́mù. Nísisìyí òun n i ẹni àkọ́kọ́ l á t i dá Ámúlẹ́kì àti Álmà lẹ́bi, òun sì jẹ́ ọkàn nínú àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ jùlọ lãrín wọn, nítorítí ó ní ìlọsíwájú púpọ̀ lórí iṣẹ́ tí ó nṣe lãrín àwọn ènìyàn nã. Nísisìyí ète àwọn agbẹjọ́rò nã ni láti ní ọ̀pọ̀ owó; wọ́n sì nrí ọ̀pọ̀ owó nípasẹ̀ iṣẹ́ tí wọ́n nṣe. 11 A gbé ètò ìṣirò owó kalẹ̀ fún àwọn ará Nífáì—Ámúlẹ́kì bá Sísrọ́mù jà—Krístì kì yíò gba àwọn ènìyàn là nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn—Àwọn tí ó bá jogún ìjọba ọ̀run nìkan ni a gbàlà—Gbogbo ènìyàn ni yíò jínde sínú ipò àìkú ayérayé—Kò sí ikú lẹ́hìn Àjĩnde. Ní ìwọ̀n ọdún 82 kí a tó bí Olúwa wa. Báyĩ sì ni ó rí nínú òfin Mòsíà pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá jẹ́ adájọ́ ti òfin,tàbí àwọn tí a yàn láti jẹ́ onídàjọ́, ní ẹ̀tọ́ láti gba owó ọya ní ìbámu pẹ̀lú àsìkò tí nwọ́n fi ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí a bá mú tọ̀ nwọ́n wá fún ìdájọ́. Nísisìyí bí ẹnìkan bá jẹ òmíràn ní gbèsè owó, tí òun kò sì san èyítí ó jẹ, tí a sì fi sun adájọ́; tí adájọ́ sì lo àṣẹ rẹ̀, tí ó sì rán àwọn oníṣẹ́ rẹ láti mú ọkùnrin nã wá sí iwájú òun; tí ó sì ṣe ìdájọ́ fún ọkùnrin nã ní ìbámu pẹ̀lú òfin àti ẹ̀rí tí nwọ́n jẹ́ síi, tí a sì fi ipá múu kí ó san gbèsè tí ó jẹ, tàbí kí a gba gbogbo ohun ìní rẹ, tàbí kí a lée jáde kúrò lãrín àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́bí olè tàbí ọlọ́ṣà. Adájọ́ nã sì gba owó ọya rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àkokò tí ó lò—ìwọ̀n wúrà kan fún ọjọ́ kan, tàbí ìwọ̀n fàdákà kan, èyítí íṣe ìwọ̀n wúrà kan; èyí sì wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin tí nwọ́n ṣe. Nísisìyí, àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn onírurú ẹyọ wúrà nwọn, àti ti fàdákà nwọn, gẹ́gẹ́bí nwọ́n ti níye lórí. Àwọn ará Nífáì ni ó sì fún nwọn lórúkọ nã, nítorítí àwọn kò ṣe ìṣirò oye-orí gẹ́gẹ́bí àwọn Jũ tí nwọ́n wà ní Jerúsálẹ́mù tií ṣe; bẹ̃ ni nwọn kò díwọ̀n gẹ́gẹ́bí àwọn Jũ; ṣùgbọ́n nwọ́n yí ìṣirò oye-orí ti nwọn padà, pẹ̀lú ìṣirò-ìwọ̀n nwọn, ní ìbámu pẹ̀lú ọkàn àti ipò tí àwọn ènìyàn nã bá wà, ní ìran kan dé òmíràn, títí dé ìjọba àwọn onídàjọ́, àwọn èyítí ọba Mòsíà ti ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀. Nísisìyí ìṣirò nã ni èyí— sénínì wúrà kan, séónì wúrà kan, ṣọ́mù wúrà kan, àti límnà wúrà kan. Sẹ́númù fàdákà kan, ámnórì fàdákà kan, ésrómù fàdákà kan àti ọ́ntì fàdákà kan. Ẹyọ sénúmù fàdákà kan jẹ́ ẹyọ sénínì wúrà kan, èyíkẽyí wọ̀n sì jẹ́ ìwọ̀n barley kan, àti pẹ̀lú ó sì wà fún ìwọ̀n onírũrú ọkà. Báyĩ iye-orí séónì kan jẹ́ ìlópo méjì iye sẹ́nínì kan. Ìwọ̀n ṣọ́mù wúrà kan sì jẹ́ ìlọ́po méjì iye-orí ìwọ̀n séonì kan. Ìwọ̀n límnà wúrà kan sì jẹ́ iye-orí gbogbo àwọn yĩ. Ìwọ̀n ámnórì fàdákà kan sí níye lórí tó sénúmù méjì. Ìwọ̀n ésrọ́mù fàdákà kan sì níye lórí tó sénúmù mẹ́rin. Ìwọ̀n ọ́ntì kan sì níye lórí tó gbogbo àwọn wọ̀nyí. Èyí sì ni iye-orí àwọn ìṣirò nwọn kékèké— Ìwọ̀n ṣíblọ́nì kan jẹ́ ìdajì sénúmù; nítorínã ìwọ̀n ṣíblọ́nì kan jẹ́ ìdajì ìwọ̀n barley kan. Ìwọ̀n ṣíblúmù kan jẹ́ ìdajì ìwọ̀n ṣíblọ́nì. Ìwọ̀n léù kan sì jẹ́ ìdajì ìwọ̀n ṣíblúmù. Báyĩ sì ni iye nwọn, gẹ́gẹ́bí ìṣirò nwọn. Báyĩ ìwọ̀n ántíónì kan ti wúrà jẹ́ ìwọ̀n mẹ́ta ṣíblónì. Nísisìyí, èyí wà fún ìdí pàtàkì láti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrè, nítorítí nwọ́n ngba owó ọya nwọn gẹ́gẹ́bí nwọ́n ṣe ṣiṣẹ́ sí, nítorínã, nwọn a máa rú àwọn ènìyàn sókè sí ìrúkèrúdò, àti onírurú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ àti ìwà búburú, pé kí nwọ́n lè rí iṣẹ́ ṣe síi, pé kí nwọ́n lè gba owó gẹ́gẹ́bí àwọn ẹjọ́ tí nwọ́n gbé wá síwáju nwọn; nítorínã ni nwọ́n ṣe nrú àwọn ènìyàn sókè tako Álmà àti Ámúlẹ́kì. Sísrọ́mù yí sì bẹ̀rẹ̀sí bí Ámúlẹ́kì lẹ́jọ́ pé: Njẹ́ ìwọ yíò dáhùn ìbẽrè díẹ̀ tí èmi yíò bí ọ́? Báyĩ Sísrọ́mù jẹ́ ènìyàn tí ó jáfáfá nínú àwọn ète èṣù, láti lè pa ohun tí ó dára run; nítorínã, ó wí fún Ámúlẹ́kì: Njẹ́ ìwọ yíò dáhùn àwọn ìbẽrè tí èmi yíò bí ọ́? Ámúlẹ́kì sì wí fún un pé: Bẹ̃ ni, tí o bá bá Ẹ̀mí-Mímọ́ Olúwa mu, èyítí ó wà nínú mi; nítorítí èmi kò ní sọ ohunkóhun tí ó lòdì sí Ẹ̀mí Mímọ́ Olúwa. Sísrọ́mù sì wí fún un pé: wọ́, óntì fàdákà mẹ́fà ni èyí, gbogbo èyí ni èmi yíò sì fi fún ọ tí ìwọ bá lè sẹ́ wíwà Ọlọ́run Ẹnití-O-Tóbi-Jùlọ. Nísisìyí Ámúlẹ́kì wípé: Á!, ìwọ ọmọ ọ̀run-àpãdì, ẽṣe tí ìwọ ndán mi wò? Ìwọ kò ha mọ̀ pé olódodo kò lè jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún irú àdánwò bí èyí? Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé kò sí Ọlọ́run? Èmi wí fún ọ, Rárá, ìwọ mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà, ṣùgbọ́n ìwọ fẹ́ràn owó jũ lọ. Àti nísisìyí ìwọ níye ti purọ́ fún mi níwájú Ọlọ́run. Ìwọ wí fún mi pé—Wo àwọn óntì mẹ́fà wọ̀nyí, tí nwọ́n níye lórí púpọ̀púpọ̀, èmi yíò fi fún ọ—nígbàtí ìwọ níi lọ́kàn rẹ láti fi wọ́n pamọ́ fún mi; tí ó sì jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ nìkan ni kí èmi ó sẹ́ Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè, kí ìwọ kí ó lè ní ìdí láti pa mi run. Àti nísisìyí kíyèsĩ, fún ìwà búburú nlá yĩ, ìwọ yíò gba èrè rẹ. Sísrọ́mù sì wí fún un pé: Ìwọ wípé Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè nbẹ bí? Ámúlẹ́kì sì wípé: Bẹ̃ni, Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè nbẹ. Báyĩ Sísrọ́mù sọ wípé: Njẹ́ ó ju Ọlọ́run kanṣoṣo tí ó nbẹ? Òun sì dáhùn pé, Rárá. Báyĩ Sísrọ́mù tún wí fún un pé: Báwo ni ìwọ ṣe mọ́ ohun wọ̀nyí? Òun sì sọ wípé: Ángẹ́lì kan ni ó ti fi nwọ́n mọ̀ fún mi. Sísrọ́mù sì tún wípé: Tani ẹni nã tí nbọ̀wá? Njẹ́ Ọmọ Ọlọ́run ha ni bí? Ó sì wí fún un pé, bẹ̃ni. Sísrọ́mù tún wípé: Njẹ́ òun yíò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn bí? Ámúlẹ́kì sì dáhùn ó sì wí fún un pé: Èmi wí fún ọ, òun kò ní ṣe èyí, nítorítí ó ṣòro fún un láti sẹ́ ọ̀rọ̀ọ rẹ̀. Nísisìyí Sísrọ́mù wí fún àwọn ènìyàn nã: Kí ẹ rántí àwọn ohun wọ̀nyí; nítorítí ó wípé Ọlọ́run kan ni ó wà; síbẹ̀ ó tún wí pé Ọmọ Ọlọ́run nbọ̀wá, ṣùgbọ́n kò ní gba àwọn ènìyàn là—bí èyítí òun ní àṣẹ láti pàṣẹ fún Ọlọ́run. Nísisìyí Ámúlẹ́kì tún wí fún un pé: Kíyèsĩ ìwọ purọ́, nítorítí ìwọ sọ wípé èmi nsọ̀rọ̀ bí ẹni tí ó ní àṣẹ láti pàṣẹ fún Ọlọ́run nítorí èmi wípé òun kì yíò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn. Èmi sì tún wí fún ọ pé òun kò lè gbà nwọ́n là nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn; nítorítí èmi kò lè sẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ, òun sì ti sọ wípé ohun àìmọ́ kan kò lè jogún ìjọba ọ̀run; nítorínã, báwo ni ẹ̀yin yíò ṣe gbàlà, àfi tí ẹ̀yin bá jogún ìjọba ọ̀run? Nítorínã, ẹ̀yin kò lè rí ìgbàlà nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín. Nísisìyí Sísrọ́mù tún wí fún un pé: Njẹ́ Ọmọ Ọlọ́run nã ni Bàbá Ayérayé nã? Ámúlẹ́kì sì wí fún un pé: Bẹ̃ni, òun ni Bàbá Ayérayé ti ọ̀run òun ayé, àti gbogbo ohuntí ó wà nínú rẹ̀; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin, ìkínní àti ìgbẹ̀hìn; Òun yíò sì wá sínú ayé láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà; òun yíò sì gba àwọn ìwà ìrékọjá àwọn tí ó gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ lé ara rẹ̀, àwọn wọ̀nyí ni nwọn yíò sì ní ìyè àìnípẹ̀kun, ìgbàlà kò sì sí fún ẹlòmíràn. Nítorínã, àwọn ènìyàn búburú wà bí ẹnipé a kò ṣe ìràpadà, àfi ti títú ìdè ikú; nítorí kíyèsĩ, ọjọ́ nã nbọ̀wá tí gbogbo ènìyàn yíò jínde kúrò nínú òkú, tí nwọn yíò sì dúró níwájú Ọlọ́run, tí a ó sì dájọ́ fún nwọn gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ ọwọ́ nwọn. Nísisìyí, ikú kan wà èyítí à npè ní ikú ti ara; ikú ti Krístì yíò sì tú ìdè ikú ti ara yĩ, tí gbogbo ènìyàn yíò fi jínde kúrò nínú ikú ti ara yĩ. Ẹ̀mí àti ara yíò tún darapọ̀ sí ipò pípé nwọn; àwọn ẹ̀yà ara àti oríkẽ ara ni a ó dá padà sí ipò nwọn, àní bí àwa ṣe wà ní àkọ́kọ́ yĩ; a ó sì mú wa dúró níwájú Ọlọ́run, tí àwa yíò sì mọ̀ gẹ́gẹ́bí àwa ṣe mọ̀ nísisìyí, tí a ó sì ní ìrántí tí ó yè kọ́ro sí gbogbo ìdálẹ́bi wa. Nísisìyí, ìdápadà sípò yí yíò wá fún gbogbo ènìyàn, gbogbo ẹ̀nítí ó dàgbà àti ẹ̀nítí ó jẹ́ ọmọdé, gbogbo ẹnití ó wà ní ìdè tàbí ní òminira, gbogbo ọkùnrin àti obìnrin, gbogbo ènìyàn búburú àti olódodo; àti pãpã, ẹyọ irun orí nwọn kan kò ní sọnù; ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni a ó da padà sí ipò rẹ pípé, bí ó ṣe wà nísisìyí, tàbí ní ti ara yĩ, tí a ó sì mú nwọn wá sí iwájú ìtẹ́ Krístì tí íṣe Ọmọ, àti Ọlọ́run tí íṣe Bàbá, àti Ẹ̀mí Mímọ́, tí íṣe Ọlọ́run Ayérayé ọ̀kanṣoṣo, láti ṣe ìdájọ́ nwọn gẹ́gẹ́bí iṣẹ wọn, ní ti rere tàbí ní ti búburú. Nísisìyí, kíyèsĩ, mo ti bá yín sọ̀rọ̀ nípa ikú ti ara, àti nípa àjĩnde ara. Èmi wí fún yín pé ara yĩ ni a ó gbé dìde sí ara àìkú, àní kúrò nínú ikú, àní kúrò nínú ikú ìkíní, sí ìyè, tí nwọn kò lè kú mọ́; tí ẹ̀mí nwọn yíò sì dàpọ̀ mọ́ ara nwọn, tí nwọn kò ní pínyà mọ́; tí gbogbo ara yíò sì di ti ẹ̀mí ati àìkú, tí nwọn kò sì lè rí ìbàjẹ́ mọ́. Nísisìyí, nígbàtí Ámúlẹ́kì ti parí àwọn ọ̀rọ̀ yí, ẹnu tún bẹ̀rẹ̀sí ya àwọn ènìyàn nã, àti Sísrọ́mù pẹ̀lú sì bẹ̀rẹ̀sí wá rìrì. Èyí sì jẹ́ òpin ọ̀rọ̀ Ámúlẹ́kì, tàbí pé èyí ni àwọn ohun tí èmi kọ. 12 Álmà bá Sísrọ́mù jà—Àwọn olótĩtọ́ níkan ni a lè fún ní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run—A ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́bí èrò, ìgbàgbọ́, ọ̀rọ̀ àti ìṣe nwọn—Àwọn ènìyàn búburú yíò gba èrè ikú ẹ̀mí—Ìpò ayé yĩ jẹ́ ti ìdánwò—Ìlànà ìràpadà mú àjĩnde nã wá, àti nípa ìgbàgbọ́, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀—Ẹnití ó bá ronúpìwàdà yíò rí ãnú gbà nípasẹ̀ Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo. Ní ìwọ̀n ọdún 82 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí nígbàtí Álmà ríi pé ọ̀rọ̀ Ámúlẹ́kì ti pa Sísrọ́mù lẹ́nu mọ́, nítorítí ó wòye pé Ámúlẹ́kì ti já ọgbọ́n irọ́ àti ẹ̀tàn rẹ̀ láti pa á run, tí ó sì ríi pé ó bẹ̀rẹ̀sĩ wá rìrì nínú ipò ẹ̀bi rẹ̀, ó la ẹnu rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀sí bã sọ̀rọ̀, àti láti fi ọ̀rọ̀ Ámúlẹ́kì mulẹ̀, àti láti se àlàyé ohun gbogbo, láti se àlàyé àwọnìwé-mímọ́ síwájú síi, ju èyítí Ámúlẹ́kì ti ṣe. Nísisìyí àwọn ọ̀rọ̀ tí Álmà sọ fún Sísrọ́mù dé etí àwọn ènìyàn yí kãkiri; nítorítí ọ̀gọ̣́rọ̀ àwọn ènìyàn nã pọ̀ púpọ̀, ó sì sọ̀rọ̀ báyĩ: Nísisìyí Sísrọ́mù, ìwọ ríi pé a ti mú ọ nínú irọ́ àti ọgbọ́n àrékérekè rẹ, nítorítí ìwọ ko purọ́ fún ènìyàn nìkan ṣùgbọ́n ìwọ ti purọ́ fún Ọlọ́run; nítorí kíyèsĩ, ó mọ̀ gbogbo èrò ọkàn rẹ, ìwọ sì ríi pé gbogbo èrò ọkàn rẹ ni Ẹ̀mí rẹ̀ ti fi hàn wá; Ìwọ sì ti rí i pé àwa mọ̀ pé ète rẹ jẹ́ àrékérekè, gẹ́gẹ́bí ti èṣù, láti purọ́ kí ó sì tan àwọn ènìyàn yí pé kí ìwọ lè gbé nwọn takò wá, láti pẹ̀gàn wa, kí nwọ́n sì lé wá jáde— Nísisìyí èyí sì jẹ́ ète ọ̀tá rẹ nnì, tí òun sì ti lo agbára rẹ̀ nínú rẹ. Nísisìyí, èmi ní ìfẹ́ pé kí ìwọ ó rántí pé ohun tí èmi bá ọ sọ, èmi sọọ́ fún ènìyàn gbogbo. Sì kíyèsĩ, èmi wí fún gbogbo yín pé èyí yĩ jẹ́ ikẹkun ọ̀tá nnì, èyítí ó ti dẹ sílẹ̀ láti mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti mú yín wá sí abẹ́ rẹ̀, pé kí ó lè fi ìdè rẹ̀ so yín yíká, pé kí òun kí ó sì so ọ́ mọ́lẹ̀ títí fi dé ìparun ayérayé, gẹ́gẹ́bí agbára ìgbèkun rẹ̀. Nísisìyí Álmà sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Sísrọ́mù bẹ̀rẹ̀sí gbọ̀n lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorítí ó ti gba ìdánilójú agbára Ọlọ́run púpọ̀púpọ̀; ó sì ti ní ìdánilójú wípé Álmà àti Ámúlẹ́kì ní ìmọ̀ nípa òun, nítorítí ó ní ìdánilójú wípé nwọn mọ́ èrò àti ète ọkàn òun; nítorítí a fún nwọn ní agbára kí nwọ́n lè mọ́ ohun wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí ti ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀. Sísrọ́mù sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìwádí tọkàn-tọkàn lọ́wọ́ nwọn, kí òun lè ní ìmọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Ó sì wí fún Álmà: Kíni ìtumọ̀ èyí tí Ámúlẹ́kì ti wí nípa àjĩnde òkú, pé gbogbo ènìyàn yíò jínde kúrò nínú ipò òkú, àwọn tí ó jẹ́ ẹni tí ó tọ àti àwọn ẹni aláìtọ́, tí a ó sì mú wọn dúró níwájú Ọlọ́run fún ìdájọ́, gẹ́gẹ́bí iṣẹ ọwọ́ nwọn. Àti nísisìyí, Álmà bẹ̀rẹ̀sí ṣe àlàyé àwọn ohun wọ̀nyí fún un pé: A fi fún ọ̀pọ̀ láti mọ́ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a fi nwọ́n sí abẹ́ òfin tí ó múná pé nwọn kò gbọ́dọ̀ fi nwọ́n hàn àfi gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ èyítí ó bá gbà fún àwọn ọmọ ènìyàn, gẹ́gẹ́bí ìgbọ́ran àti ìtẹramọ́ èyítí nwọ́n bá fi fún un. Nítorínã, ẹnití ó bá sé àyà rẹ le, èyĩ yí ni yíò gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àìkún; ẹnití kò bá sì sé àyà rẹ le, òun ni a ó fún ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ nã, títí a ó fi fún un ní ìmọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, títí yíò fi mọ̀ nwọ́n ní kíkún. Àwọn tí nwọn bá sì sé àyà nwọn le, àwọn ni a ó fún ní àìkún ọ̀rọ̀ nã, títí tí nwọn kò lè mọ́ ohunkóhun nípa ohun ìjìnlẹ̀ rẹ̀; tí a ó sì mú nwọn ní ìgbèkùn sí ipa èṣù, tí a ó sì tọ́ nwọ́n nípa ìfẹ́ rẹ̀ sí ìhà ìparun. Nísisìyí, èyí ni à npè ní ìdè ẹ̀wọ̀n ọ̀run àpãdì. Ámúlẹ́kì sì ti sọ̀rọ̀ ní pàtó nípa ikú, àti àjĩnde kúrò ní ipò ikú sí ipò àìkú, àti mímú ènìyàn wá sí iwájú itẹ Ọlọ́run, láti dá lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ wa. Bí ọkàn wa bá sì ti sé le, bẹ̃ni, bí àwa bá ti sé ọkàn wa le sí ọ̀rọ̀ nã, tí kò sì sí nínú wa, bẹ̃ sì ni ipò wa yíò sì di ẹni ìdálẹ́bi. Nítorítí ọ̀rọ̀ wa yíò dá wa lẹ́bi, bẹ̃ni gbogbo ìṣẹ wa ni yíò dá wa lẹ́bi; àwa kò ní wà láìlábàwọ́n; àwọn èrò ọkàn wa yíò sì dá wa lẹ́bi pẹ̀lú; nínú ipò búburú yĩ àwa kì yíò lè gbé ojú sókè wo Ọlọ́run; àwa yíò sì kún fún ayọ̀ tí àwa bá pàṣẹ fún àpáta àti àwọn òkè pé kí nwọ́n wó lù wá, kí àwa lè sá pamọ́ kúrò níwájú rẹ̀. Ṣùgbọ́n, èyí kò lè rí bẹ̃; a níláti jáde wá, kí a dúró níwájú rẹ̀ nínú ògo rẹ̀, àti nínú agbára rẹ̀, àti nínú títóbi rẹ̀, àti ọlá-nlá àti ìjọba rẹ̀, tí yíò sì fi ìtìjú wa hàn títí ayé pé o tọ́ ni ìdájọ́ rẹ̀; pé òun tọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, àti pé òun nṣãnú fún àwọn ọmọ ènìyàn gbogbo, àti pé òun ní agbára láti gba ẹnìkẹ́ni tí ó bá gba orúkọ òun gbọ́, tí ó sì nṣe iṣẹ́ èyítí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, èmi wí fún un yín pé lẹ́hìn èyí ni ikú, àní ikú kejì èyítí íṣe ikú ti ẹ̀mí; èyítí íṣe àkokò tí ẹnikẹni tí ó bá kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nípa ikú ti ara, yíò kú ikú ti ẹ̀mí pẹ̀lú; bẹ̃ni, yíò kú níti àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òdodo. Èyĩ ni ìgbà nã tí ìrora nwọn yíò dàbĩ ti adágún iná àti imí ọjọ́, ọ̀wọ́ iná èyítí ó nru sókè láé àti láéláé nígbànã ni a ó gbé nwọn dè mọ́lẹ̀ sí ìparun àìlópin, gẹ́gẹ́bí agbára àti ìgbèkun Sátánì, ẹnití ó ti tẹ̀ nwọ́n bá sí ìfẹ́ẹ rẹ̀. Ní ìgbà nã mo wí fún yín, nwọn yíò wà bí ẹni pé a kò ṣe ìràpadà; nítorípé a kò lè rà nwọ́n padà, ní ìbámu pẹ̀lú àìṣègbè Ọlọ́run; nwọn kò sì lè kú, nítorípé kò sí ìdibàjẹ́ mọ́. Nísisìyí, ó sì ṣe nígbàtí Álmà ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní sísọ, ẹnu túbọ̀ ya àwọn ènìyàn nã síi; Ṣùgbọ́n ẹnìkan wà tí à npè ní Ántíónà, ẹnití ó jẹ́ alákọ́so àgbà lãrin nwọn, ó jáde ó sì wí fún un pé: Kíni èyí tí ìwọ wí, pé ènìyàn yíò dìde kúrò ní ipò òkú tí yíò sì yípadà kúrò ní ipò-òkú ara yĩ sí ipò-àìkú, pé ẹ̀mí kò lè kú? Kíni ìwé-mímọ́ túmọ̀ sí, èyítí ó sọ wípé Ọlọ́run fi kérúbímù pẹ̀lú idà iná sí apá ìlà-oòrùn ọgbà Édẹ́nì, kí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ máṣe wọ inú ibẹ̀ kí nwọ́n sì jẹ nínú èso igi ìyè nã, kí nwọn sì wà títí láéláé? Àwa sì ríi pé kò sí ọ̀nà tí nwọ́n fi lé wa títí láéláé. Nísisìyí, Álmà wí fún un pé: Èyí ni ohun tí èmi ṣetán láti ṣe àlàyé rẹ̀. Nísisìyí àwa ríi pé Ádámù ṣubú nípa jíjẹ nínú èso àìgbọdọ̀jẹ jẹ, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; báyĩ ni àwa sì ríi, pé nípa ìṣubú rẹ̀, gbogbo ènìyàn di ẹni ègbé àti ẹni ìṣubú. Nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín pé bí ó bá ṣeéṣe pé Ádámù jẹ nínú èso igi ìyè nã ní ìgbà nã, ikú kì bá ti wà, ọ̀rọ̀ kò bá sì jẹ́ òfo, tí yíò sì ṣe Ọlọ́run ní òpùrọ́, nítorítí ó wípé: Tí ìwọ bá jẹẹ́, ìwọ yíò kú dájúdájú. Àwa sì ríi pé ikú dé bá ọmọ-ènìyàn, bẹ̃ni, ikú èyítí Ámúlẹ́kì ti sọ nípa rẹ̀, èyítí íṣe ikú ti ara; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àkokò kan wà tí a fún ọmọ ènìyàn, nínú èyítí ó lè ronúpìwàdà, nítorínã, ayé yĩ jẹ́ ipò ìdánwò; àkokò tí ó múrasílẹ̀ láti bá Ọlọ́run pàdé; àkokò láti múrasílẹ̀ fún ipò àìlópin nnì èyítí àwa ti sọ nípa rẹ̀, èyítí íṣe lẹ́hìn àjĩnde òkú. Nísisìyí, tí kò bá ṣe ti ìlànà ìràpadà, èyítí a ti fi lélẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, kì bá ti sí àjĩnde òkú; ṣùgbọ́n ìlànà ìràpadà kan wà tí a fi lélẹ̀, èyítí yíò mú àjĩnde kúrò nínú ipò òkú wá sí ìmúṣẹ, èyítí a ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, tí o bá ti rí bẹ̃ pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti lọ jẹ lára igi ìyè nã nwọn ìbá ti wà nínú ipò ìròbìnújẹ́ títí láéláé, nítorítí nwọn kò ní ipò ìmúrasílẹ̀; nítorínã ìlànà ìràpadà ìbá ti jẹ́ asán, tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ìbá sì ti jẹ́ òfo tí kò sì já mọ́ ohunkóhun. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èyí kò rí bẹ̃; ṣùgbọ́n a yàn fún ènìyàn pé nwọ́n níláti kú; àti pé lẹ́hìn ikú, nwọ́n níláti wá sí ìdájọ́, àní ìdájọ́ nnì èyítí àwa ti sọ nípa rẹ̀, èyítí íṣe òpin. Lẹ́hìn tí Ọlọ́run sì ti yàn án pé kí àwọn ohun wọ̀nyí dé bá ènìyàn, kíyèsĩ, nigbanã ó ríi pé ó tọ́ fún ènìyàn láti mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó ti yàn fún nwọn; Nítorínã ó rán àwọn ángẹ́lì láti bá nwọn sọ̀rọ̀, tí nwọ́n sì jẹ́ kí ènìyàn rí nínú ògo rẹ̀. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà nã lọ síwájú láti ké pé orúkọ rẹ̀; nítorínã Ọlọ́run nbá ènìyàn sọ̀rọ̀, òun sì fi ìlànà ìràpadà hàn nwọ́n, èyítí a ti pèsè sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé; èyí ni ó sì fi hàn nwọ́n gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ nwọn à t i ìrònúpìwàdà àti iṣẹ́ mímọ́ nwọn. Nítorí-eyi, ó fún ènìyàn ní òfin, nítorípé nwọ́n ti rékọjá sí òfin àkọ́kọ́ nípa ti àwọn ohun tí íṣe ti ara, tí nwọ́n sì dàbí àwọn ọlọ́run, tí nwọ́n sì mọ́ rere yàtọ̀sí búburú, tí nwọ́n sì gbé ara nwọn sí ipò láti hùwà, tàbí tí a gbé nwọn sí ipò láti hùwà gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú àti ìdùnnú nwọn, bóyá láti ṣe búburú tàbí láti ṣe rere— Nítorínã Ọlọ́run fún nwọn ní àwọn òfin, lẹ́hìn tí ó ti fi ìlànà ìràpadà hàn nwọ́n, pé kí nwọ́n máṣe ṣe búburú, èrè èyítí íṣe ikú kejì, tĩ ṣe ikú ayérayé nípa àwọn ohun tí íṣe ti òdodo; nítorípé lórí èyí ni ìlànà ìràpadà nã kó lè ni ágbára, nítorítí àwọn iṣẹ́ àìṣègbè kò lè parun, gẹ́gẹ́bí dídára Ọlọ́run tí ó tóbi jùlọ. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ké pe ènìyàn, ní orúkọ Ọmọ rẹ̀, (èyítí íṣe ìlànà ìràpadà tí a ti fi lélẹ̀) wípé: Tí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà, tí ẹ kò sì sé ọkàn yín le, ìgbànã ni èmi yíò ṣãnú fún un yín, nípasẹ̀ Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo; Nítorínã, ẹnìkẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà, tí kò sì sé ọkàn rẹ le, òun ni yíò rí ãnú gbà nípasẹ̀ Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo, sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo; àwọn yĩ ni nwọn yíò sì bọ́ sínú ìsinmi mi. Ẹnìkẹ́ni tí yíò bá sì sé ọkàn rẹ le, tí yíò ṣe búburú, kíyèsĩ, èmi yíò búra nínú ìbínú mi pé òun kò ní bọ́ sínú ìsinmi mi. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín, pé bí ẹ̀yin bá sé ọkàn yín le, ẹ̀yin kò lè bọ́ sínú ìsinmi Olúwa; nítorínã ìwà búburú yín múu bínú tí ó sì rán ìbínú rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lé yín lórí gẹ́gẹ́bí ìmúbínú àkọ́kọ́ bẹ̃ni, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà ìmúbínú ìkẹhìn bĩ ti ìgbà àkọ́kọ́, títí dé ìparun ayérayé ti ẹ̀míi yín; nítorínã, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, títí dé ikú ìkẹhìn, àti ti àkọ́kọ́. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, níwọ̀n ìgbàtí àwa ti mọ́ àwọn ohun wọ̀nyí, àti pé òtítọ́ ni nwọn íṣe, ẹ jẹ́ kí a ronúpìwàdà,kí ẹ̀yin má sé ọkàn an yín le, kí àwa ma dan Olúwa Ọlọ́run wa wò láti fa ìbínú rẹ̀ lé wa lórí nínú àwọn òfin rẹ̀ kejì wọ̀nyí tí ó fún wa; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a wọ inú ìsinmi Ọlọ́run lọ, èyítí a ti pèsè sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ. 13 A yan àwọn ènìyàn sí ipò olórí àlùfã nítorí ìgbàgbọ́ nwọn tí ó pọ̀ àti iṣẹ́ rere nwọn—Nwọ́n wà láti kọ́ni ní àwọn òfin-Ọlọ́run—nípa ìwà òdodo a sọ nwọ́n di mímọ́, nwọ́n sì bọ́ sínú ìsinmi Olúwa—Mẹ́lkisédékì jẹ́ ọ̀kan nínú nwọn—Àwọn ángẹ́lì sì nmú ìhìn-rere ayọ̀ wá jákè-jádò ilẹ̀ nã—Nwọn yíò fi ìgbà bíbọ̀ Krístì nítọ́tọ́ hàn. Ní ìwọ̀n ọdún 82 kí a tó bí Olúwa wa. Àti pẹ̀lú, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi yíò sún ọkàn an yín síwájú sí àkokò ti Olúwa Ọlọ́run fún àwọn ọmọ rẹ̀ ni àwọn òfin wọ̀nyí; èmi yíò sì fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí pé Olúwa Ọlọ́run yan àwọn àlùfã, ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ mímọ́ rẹ̀, èyítí ó wà ní ẹgbẹ́ ti Ọmọ rẹ̀, láti kọ́ àwọn ènìyàn nã ni àwọn nkan wọ̀nyí. A sì yan àwọn àlùfã nnì ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ ti Ọmọ rẹ̀, ní ọ̀nà tí àwọn ènìyàn nã yíò fi mọ́ ọ̀nà ti wọn yio gbà ní ìrètí nínú Ọmọ rẹ̀ fún ìràpadà. Báyĩ ṣì ni ipa ọ̀nà tí a ṣe yàn nwọ́n—tí a ti pè nwọ́n, tí a sì múra nwọn sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run, nítorí ìgbàgbọ́ nwọn tí ó pọ̀ tayọ àti iṣẹ́ rere nwọn; ní ọ̀nà èkíní, tí a fi nwọ́n sílẹ̀ láti yan rere tàbí búburú; nítorínã nígbàtí nwọ́n ti yàn rere, tí nwọ́n sì fi ìgbàgbọ́ tí ó tayọ hàn, a sì pè nwọ́n pẹ̀lú ìpè mímọ́, bẹ̃ni, pẹ̀lú ìpè mímọ́ nnì èyítí a ti múra rẹ̀ sílẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìràpadà tí a ti ṣe ìmúrasílẹ̀ rẹ̀ fún irú nwọn. Báyĩ sì ni a ti pè nwọ́n sí ìpè mímọ́ yí ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nwọn, nígbàtí àwọn míràn kẹ̀hìn sí Ẹ̀mi Ọlọ́run nítorí líle ọkàn nwọn àti ìfọ́jú inú nwọn, nítorí tí kò bá jẹ́ fún ìdí èyí, nwọn ìbá ní ọ̀pọ̀ ànfãní gẹ́gẹ́bí ti àwọn arákùnrin nwọn. Tàbí ní àkótán, ní ọ̀nà èkíní, nwọ́n wà bákannã pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn; báyĩ sì ni ìpè mímọ́ yí, tí a ti pèsè sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún àwọn ẹnití kò ní se ọkàn nwọn le, èyítí ó wà tĩ sì íṣe nípasẹ̀ ètùtù Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo, ẹníti a ti pèsè sílẹ̀— Tí a sì ti pè nwọ́n báyĩ nípa ìpè mímọ́ yí, tí a sì yàn nwọ́n sí ipò-àlùfã gíga ti ẹgbẹ́ mímọ́ Ọlọ́run, láti kọ́ àwọn ọmọ ènìyàn ní àwọn òfin rẹ̀, kí nwọ́n sì lè bọ́ sínú ìsinmi rẹ̀— Ipò-àlùfã gíga yĩ tí ó jẹ́ ti ẹgbẹ́ Ọmọ rẹ̀, ẹgbẹ́ èyítí ó ti wà láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé; tàbí kí a wípé, ó jẹ́ èyítí kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọdún, tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ láti ayérayé dé ayérayé, gẹ́gẹ́bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ lórí ohun gbogbo— Báyĩ ni a ṣe yàn nwọ́n ní ipa ọ̀nà yí—tí a pè nwọ́n pẹ̀lú ìpè mímọ́, tí a sì yàn nwọ́n pẹ̀lú ìlànà mímọ́, tí nwọ́n sì gba ipò-àlùfã gíga ti ẹgbẹ́ mímọ́, ìpè àti yíyàn, àti ipò-àlùfã gíga sì wà láìní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin— Báyĩ ni nwọ́n sì jẹ́ olórí àlùfã títí láéláé, ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ ti Ọmọ, ẹnítí íṣe Bíbí kanṣoṣo tiBàbá, ẹnití kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọdún, ẹnití ó kún fún ọ́re-ọ̀fẹ́, ìṣòtítọ́ àti òtítọ́. Bẹ̃ sì ni ó rí. Àmin. Nísisìyí, gẹ́gẹ́bí èmi ti sọ nípa ti ẹgbẹ́ mímọ́ nnì, tàbí ipò olórí àlùfã yí, a yan ọ̀pọ̀lọpọ̀, nwọ́n sì di àlùfã gíga ti Ọlọ́run; èyítí íṣe nípasẹ̀ títóbi ìgbàgbọ́ nwọn àti ìrònúpìwàdà, àti òdodo nwọ́n níwájú Ọlọ́run, nítorítí nwọ́n yàn láti ronúpìwàdà kí nwọ́n sì ṣe iṣẹ́ òdodo, kí nwọ́n má bã ṣègbé; Nítorínã ni a fi pè nwọ́n ní ti ẹgbẹ́ mímọ́ yí, tí a sì yà nwọ́n sí mímọ́, tí a sì fọ aṣọ nwọn mọ́ di funfun nípa ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn. Nísisìyí, lẹ́hìn tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti yà nwọ́n sí mímọ́, tí aṣọ nwọn ti di funfun, tí ó sì ti mọ́, tí ó sì wà láìlẽrĩ níwájú Ọlọ́run, nwọn kò lè bojú wo ẹ̀ṣẹ̀ àfi pẹ̀lú ìkóríra; àwọn púpọ̀ sí wà, tí nwọ́n pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, tí a sọ di mímọ́ tí nwọ́n sì ti bọ́ sínú ìsinmi Olúwa Ọlọ́run nwọn. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, kí ẹ̀yin sì so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ̀yin nã lè bọ́ sínú ìsinmi nã. Bẹ̃ni, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ àní gẹ́gẹ́bí àwọn ènìyàn nnì, ní ìgbà Mẹ́lkisédékì, ẹnití íṣe olórí àlùfã pẹ̀lú, ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ kannã èyítí mo ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ẹnití ó gba oyè-àlùfã gíga nnì títí láé. Mẹ́lkisédékì yĩ kannã ni Ábráhámù san ìdámẹ̃wá fún; bẹ̃ni, àní bàbá wa Ábráhámù san ìdámẹ́wá lórí ohun iní rẹ gbogbo. Nísisìyí, àwọn ìlànà yí ni a gbé kalẹ̀ ní ọ̀nà yí, pé kí àwọn ènìyàn lè fojúsọ́nà sí Ọmọ Ọlọ́run nã, èyítí íṣe irú ẹgbẹ́ tirẹ̀ kan, tàbí tĩ ṣe ẹgbẹ́ tirẹ̀, èyí sì rí bẹ̃ kí nwọ́n lè fojúsọ́nà síi fún ìràpadà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, kí nwọn kí ó lè wọ inú ìsinmi Olúwa. Nísisìyí, Mẹ́lkisédékì yĩ jẹ́ ọba lórí ilẹ̀ Sálẹ́mù; àwọn ènìyàn rẹ̀ sì ti hu ìwà àìṣedẽdé àti ẽrí lọ́pọ̀lọpọ̀; bẹ̃ni, nwọ́n ti ṣáko lọ; nwọ́n sì kún fún onírurú ìwà búburú; Ṣùgbọ́n nítorítí Mẹ́lkisédékì ní ìgbàgbọ́ púpọ̀, tí ó sì gboyè ipò-àlùfã gíga ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ mímọ́ Ọlọ́run, ó sì wãsù ìrònúpìwàdà sí àwọn ènìyàn rẹ̀. Sì kíyèsĩ, nwọ́n ronúpìwàdà; Mẹ́lkisédékì sì fi àlãfíà lélẹ̀ ní orí ilẹ̀ nã ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀; nítorínã ni a ṣe pẽ ní ọmọ-aládé àlãfíà, nítorítí òun ní í ṣe ọba Sálẹ́mù; òun sì jọba lábẹ́ bàbá rẹ̀. Nísisìyí, àwọn ti nwọ́n wà ṣãjú rẹ̀ pọ̀, àti pẹ̀lú, àwọn tí nwọ́n wà lẹ́hìn rẹ pọ̀, ṣùgbọ́n kò sí èyítí ó tóbi jũ; nítorínã, nípa rẹ̀ ni a ti kọ àkọsílẹ̀ ju ti ẹlòmíràn lọ. Nísisìyí, kò sí ìdí fún mi láti tẹnumọ́ ohun yĩ; èyí tí èmi ti sọ ti tó. Kíyèsĩ, àwọn ìwé mímọ́ wà níwájú yín; tí ẹ̀yin bá sì yí nwọn po, yíò já sí ìparun fún yín. Àti nísisìyí, ó sì ṣe, nígbàtí Álmà ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún nwọn, ó na ọwọ́ rẹ jáde sí nwọn, ó sì kígbe ní ohùn rara, wípé: Àsìkò ti tó láti ronúpìwàdà, nítorítí ọjọ́ ìgbàlà ti dé tán; Bẹ̃ ni, ohùn Olúwa láti ẹnu àwọn ángẹ́lì, sì kéde fún gbogbo orílẹ̀-èdè; bẹ̃ni, ó kéde rẹ̀, pé kí nwọ́n lè ní ìró ayọ̀ inú dídùn púpọ̀púpọ̀; bẹ̃ni, ó sì nró ìró ayọ̀nlá yĩ lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo, bẹ̃ni, àní sí àwọn tí a fọ́nká kiri yíká gbogbo orí ilẹ̀ ayé; nítorí-eyi ni nwọ́n ṣe tọ̀ wá wá. Nwọ́n sì fi nwọ́n yé wa yékéyéké kí ó bá lè yé wa pé àwa kò lè ṣẹ̀; èyí sì rí bẹ̃ nítorípé àwa jẹ́ aṣáko nínú ilẹ̀ àjòjì; nítorínã, àwa rí ọ̀pọ̀ ọjú rere Olúwa, nítorítí àwa ní ìró ayọ̀ yí tí nwọ́n kéde fún wa nínú gbogbo ọgbà àjàrà wa. Nítorí kíyèsĩ, àwọn ángẹ́lì nkéde rẹ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àkokò yĩ ní orí ilẹ̀ wa; èyí sì wà fún ìpalẹ̀mọ́ ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn láti gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àkokò nã tí yíò dé nínú ògo rẹ̀. Àti nísisìyí àwa ndúró láti gbọ́ ìkéde ìròhìn ayọ̀ nã láti ẹnu àwọn ángẹ́lì nípa bíbọ̀ rẹ̀; nítorítí àkokò nã nbọ̀, àwa kò mọ̀ bí yíò ṣe yá sí. Olúwa ìbá sì jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà tèmi; ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ rí bẹ̃ ṣãjú ìgbà yí, tàbí lẹ́hìn rẹ̀, nínú èyí ni èmi yíò yọ̀. Yíò sì jẹ́ mímọ̀ fún àwọn ẹni títọ́ àti mímọ́, láti ẹnu àwọn ángẹ́lì, ní àkokò bíbọ̀ rẹ̀, kí ọ̀rọ̀ àwọn bàbá wa lè ṣẹ, gẹ́gẹ́bí èyítí nwọ́n ti sọ nípa rẹ̀, èyítí íṣe nípa ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ tí ngbé inú nwọn. Àti nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi nfẹ́ tọkàn-tọkàn, bẹ̃ni, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àníyàn ọkàn títí fi dé ìrora, pé kí ẹ̀yin fi ètí sílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ̀yin sì fi ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, kí ẹ ṣíwọ́ ìfàsẹhìn ìrònúpìwàdà yín; Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, kí ẹ̀yin sì pe orúkọ rẹ̀ mímọ́, kí ẹ máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà-gbogbo, kí a má bã dán yín wò ju agbára yín lọ, kí ẹ̀yin lè gba ìtọ́sọ́nà Ẹ̀mí Mímọ́ báyĩ, kí ẹ̀yin sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ọkàn, oníwà-pẹ̀lẹ́, aláìgbéraga, ìfaradà, kí ẹ kún fún ìfẹ́, àti ìlọ́ra gbogbo; Kí ẹ̀yin kí ó ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa; kí ẹ̀yin kí ó ní ìrètí pé ẹ̀yin yíò gba ìyè àìnípẹ̀kun; kí ẹ̀yin ó sì ní ìfẹ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nínú ọkàn yín, kí a lè gbé yín sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn kí ẹ̀yin sì bọ́ sínú ìsinmi rẹ̀. kí Olúwa kí ó fún yín ní ìrònúpìwàdà, kí ẹ̀yin kí ó máṣe fa ìbínú rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sóríi yín, kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe wà ní dídè nínú ìdè ọ̀run àpãdì; kí ẹ̀yin kí ó máṣe jìyà ikú kejì. Álmà sì sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀ síwájú si sí àwọn ènìyàn nã, èyítí a kò kọ sínú ìwé yĩ. 14 A gbé Álmà pẹ̀lú Ámúlẹ́kì sọ sínú túbú, a sì nà nwọ́n—Àwọn tí ó gba Olúwa gbọ́ pẹ̀lú àwọn ìwé mímọ́ nwọn ni a jó níná—Àwọn ajẹ́rĩkú yi ni Olúwa gbà sínú ògo—Ògiri ọgbà ẹ̀wọ̀n nã ya, ó sì wó lulẹ̀—A kó Álmà àti Ámúlẹ́kì yọ, a sì pa àwọn onínúnibíni nwọn. Ní ìwọ̀n ọdún 82–81 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí ó ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sísọ fún àwọn ènìyàn nã, púpọ̀ nínú nwọn sì gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ronúpìwàdà, nwọ́n sì nwá inú ìwé-mímọ́. Ṣùgbọ́n púpọ̀ nínú nwọn ni nwọ́n fẹ́ kí a pa Álmà pẹ̀lú Ámúlẹ́kì run; nítorítí nwọn nbínú sí Álmà nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó yè koro sí Sísrọ́mù; nwọ́n sì tún sọ wípé Ámúlẹ́kì ti purọ́ fúnnwọn, ó sì ti ta ko òfin nwọn, àti àwọn agbẹjọ́rò àti àwọn adájọ́ nwọn pẹ̀lú. Nwọn sì tún nbínú sí Álmà pẹ̀lú Ámúlẹ́kì; nítorítí nwọ́n ti jẹ́ ẹ̀rí ní pàtó sí ìwà búburú nwọn, nwọ́n nwá ọ̀nà láti pa nwọ́n ní ìkọ̀kọ̀. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí nwọn kò ṣe èyí; ṣùgbọ́n nwọ́n mú nwọn, nwọ́n sì dè nwọ́n pẹ̀lú okùn tí ó yi, tí nwọ́n sì mú nwọn wá sí iwájú adájọ́ àgbà ilẹ̀ nã. Àwọn ènìyàn nã sì jáde lọ jẹ́ ẹ̀rí takò nwọ́n—nwọn njẹ́rĩ pé nwọ́n kẹ́gàn òfin, àti àwọn agbẹjọ́rò àti àwọn adájọ́ ilẹ̀ nã, àti bákannã gbogbo àwọn tí ó wà lórí ilẹ̀ nã; nwọ́n sì jẹ́rĩ pé Ọlọ́run kanṣoṣo ni ó wà, tí yíò sì rán ọmọ rẹ̀ sí ãrin àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n òun kò níláti gbà nwọ́n là; àti púpọ̀ irú ohun báyĩ ni àwọn ènìyàn nã jẹ́rĩ sí tako Álmà àti Ámúlẹ́kì. Àwọn wọ̀nyí ni nwọ́n ṣe níwájú adájọ́ àgbà ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí ẹnu ya Sísrọ́mù nípa àwọn ohun tí nwọ́n ti sọ; òun sì mọ̀ nípa ìfọ́jú ọkàn nwọn, èyítí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ rí bẹ̃ lãrín àwọn ènìyàn nítorí ọ̀rọ̀ irọ́ rẹ̀ gbogbo; ọkàn rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀sí gbọgbẹ́ nínú ẹ̀bi rẹ̀; bẹ̃ni, ìrora ipò òkú sì bẹ̀rẹ̀sí yíi po. Ó sì ṣe tí ó bẹ̀rẹ̀sí kígbe sí àwọn ènìyàn nã wípé: Ẹ kíyèsĩ, èmi jẹ̀bi, àwọn arákùnrin wọ̀nyí sì wà láìlábàwọ́n níwájú Ọlọ́run. Ó sì bẹ̀rẹ̀sí ṣípẹ̀ fún nwọn láti ìgbà nã lọ; ṣùgbọ́n nwọ́n takọ́, wípé: Ìwọ pẹ̀lú ha ti gba èṣù? Nwọ́n sì tu itọ́ síi, nwọ́n sì jũ síta kúrò lãrín nwọn, pẹ̀lú àwọn tí ó gba ọ̀rọ̀ ti Álmà àti Ámúlẹ́kì sọ gbọ́; nwọ́n sì sọ nwọ́n síta, nwọ́n sì rán àwọn ènìyàn kí nwọ́n sọ nwọ́n ní òkúta. Nwọ́n sì kó àwọn aya nwọn àti àwọn ọmọ jọ, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́, tàbí tí a ti kọ́ pé kí ó gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́, nwọ́n jù nwọ́n sínú iná; nwọ́n sì mú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ nwọn jáde nínú èyítí àwọn ìwé-mímọ́ wà, nwọ́n jù nwọ́n sínú iná pẹ̀lú, kí nwọ́n lè jóná kí nwọ́n sì parun nínú iná. Ó sì ṣe tí nwọ́nmúÁlmà pẹ̀lú Ámúlẹ́kì, tí nwọ́n sì gbé nwọn jáde lọ sí ibi ikú àwọn ajẹ́rĩ ikú, kí nwọ́n lè ṣe ìjẹ́rĩsí ìparun àwọn tí nwọ́n jó pẹ̀lú. Nígbàtí Ámúlẹ́kì rí ìrora àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tí nwọn njóná nínú iná, òun nã jẹ̀rora; ó sì wí fún Álmà: báwo ni àwa ó ṣe máa wo ohun búburú yíi? Nítorínã, jẹ́ kí a na ọwọ́ wa jáde; kí a lo agbára Ọlọ́run èyítí ó wà nínú wa, kí a sì gbà nwọ́n lọ́wọ́ iná yĩ. Ṣùgbọ́n Álmà wí fún un pé: Ẹ̀mí Mímọ́ rọ̀ mí láti má na ọwọ́ mi jáde, nítorí kíyèsĩ, Olúwa gbà nwọ́n sọ́dọ̀ ara rẹ̀, nínú ògo; òun sì gbà pé kí nwọ́n ṣe èyí, tàbí pé kí àwọn ènìyàn nã ṣe ohun yĩ sí nwọn, ní ìbámu pẹ̀lú líle ọkàn an nwọn, kí ìdájọ́ tí òun yíò ṣe fún nwọn nínú ìbínú rẹ̀ lè tọ́; kí ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ nnì s‘ilè dúró gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí tako nwọn, bẹ̃ni, kí ó sì kígbe rara takò nwọ́n ní ọjọ́ ìkẹhìn. Nísisìyí, Ámúlẹ́kì wí fún Álmà: Kíyèsĩ, boyá nwọn yíò jó àwa nã níná. Álmà sì wí pé: Kí ó rí bẹ̃ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ Olúwa. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, iṣẹ́ wa kòì tĩ parí; nítorínã nwọn kò lè jó wa níná. Nísisìyí ó sì ṣe, nígbàtí ara àwọn tí a ti jù sínú iná ti jóná, pẹ̀lú àwọn ìwé-àkọsílẹ̀ tí a jù sínú rẹ pẹ̀lú nwọn, adájọ́ àgbà ilẹ̀ nã wá ó sì dúró síwájú Álmà àti Ámúlẹ́kì, bí a ti dè nwọ́n; ó sì gbá nwọn lẹ́nu pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, ó sì wí fún nwọn pé: Lẹ́hìn ohun tí ẹ̀yin ti rí, njẹ́ ẹ̀yin yíò tún wãsù sí àwọn ènìyàn yí, pé a o gbé nwọn jù sínú adágún iná àti imí ọjọ́? Kíyèsĩ, ẹ̀yin ríi pé ẹ̀yin kò lágbára láti gba àwọn tí a ti jù sínú iná là; bẹ̃ sì ni Ọlọ́run kò gbà nwọ́n nítorítí òun kannã ni ẹ gbàgbọ́. Adájọ́ nã sì tún gbá nwọn lẹ́nu, ó sì bẽrè: Kíni ẹ̀yin rí sọ fún ara yín? Nísisìyí, adájọ́ yĩ jẹ́ ti ipa ìgbàgbọ́ ti Néhórì, ẹnití ó pa Gídéónì. Ó sì ṣe tí Álmà àti Ámúlẹ́kì ko dáa lóhùn ohunkóhun; ó sì tún lù nwọn, ó sì jọ̀wọ́ nwọn lé ọwọ́ àwọn oníṣẹ́ rẹ, kí nwọ́n jù nwọ́n sínú túbú. Nígbàtí nwọn sì ti jù nwọ́n sínú túbú fún ọjọ́ mẹta, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbẹjọ́rò, àti àwọn adajọ, ati àwọn alufaa, ati àwọn olùkọ́ni, tí nwọn jẹ́ ti ipa Néhórì wá; nwọ́n sì wá sínú túbú láti wò nwọ́n, nwọ́n sì bẽrè ọ̀rọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ nwọn; ṣùgbọ́n nwọn kò dáhùn ohunkún. Ó sì ṣe tí adájọ́ nã dide níwájú nwọn, tí ó wípé: Kíni ìdíi rẹ̀ tí ẹ̀yin kò dáhùn ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn yí? Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé èmi ní agbára láti jù yín sínú iná? Ó sì pã láṣẹ fún nwọn pé kí nwọ́n sọ̀rọ̀; ṣùgbọ́n nwọn kò dáhùn ohunkóhun. Ó sì ṣe tí nwọ́n kúrò níbẹ̀, tí nwọ́n sì bá ọ̀nà tiwọn lọ, ṣùgbọ́n nwọn padà ní ọjọ́ kejì; adájọ́ nã sì tún gbá nwọn lẹ́nu. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì jáde wá pẹ̀lú, nwọ́n sì nà nwọ́n, nwọ́n wípé: Njẹ́ ẹ̀yin yíò tún dìde kí ẹ sì rojọ́ mọ́ àwọn ènìyàn yí, kí ẹyin sì tako òfin wa? Tí ẹ̀yin bá ní irú agbára nlá báyĩ, ẹyin kò ṣe lè gba ara yín. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun báyĩ ni nwọ́n nsọ, wọn pa ehin keke si wọn, tí nwọ́n sì ntutọ́ sí nwọn lara, tí nwọ́n wípé: Báwo ni àwa yíò ṣe rí nígbàtí a bá dá wa lẹ́bi? Àti pẹ̀lú irú àwọn ohun báyĩ, bẹ̃ni, onírũrú ohun báyĩ ni nwọ́n nsọ sí nwọn; bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni nwọ́n sì ṣe nfi nwọ́n ṣe ẹlẹ́yà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. Nwọn kò sì fún nwọn ní oúnjẹ, kí ẹbi lè pa nwọ́n, pẹ̀lú omi, kí òrùngbẹ lè gbẹ nwọ́n; nwọ́n sì gba aṣọ lára wọn tí nwọ́n wà ní ìhọ́hò; báyĩ ni nwọ́n sì dì nwọ́n pẹ̀lú okùn yíyi, tí nwọ́n sì ha nwọn mọ́ inú túbú. Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí nwọ́n ti jìyà báyĩ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, (ó sì jẹ́ ọjọ́ kejìlá, ní oṣù kẹẹ̀wá, ní ọdún kẹẹ̀wá ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ará Nífáì) tí adájọ́ àgbà lórí ilẹ̀ Amonáíhà àti púpọ̀ nínú àwọn olùkọ́ni nwọn, àti àwọn agbẹjọ́rò nwọn, tọ Álmà àti Ámúlẹ́kì lọ nínú túbú níbití a gbé dì nwọ́n pẹ̀lú okùn. Adájọ́ àgbà nã sì dúró níwájú nwọn, ó sì tún nà nwọ́n, ó sì wí fún nwọn pé: Tí ẹ̀yin bá ní agbára Ọlọ́run, ẹ gba ara yín kúrò nínú ìdè yìi, nígbànã ni àwa yíò gbàgbọ́ pé Olúwa yíòpa àwọn ènìyàn yí run gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ yín. Ó sì ṣe tí gbogbo nwọn sì kọjá lọ láti nà nwọ́n, tí nwọ́n sì nsọ ohun kannã, títí fi dé ẹnití ó kẹ́hìn; nígbàtí ẹnití ó kẹ́hìn sì ti sọ̀rọ̀ sí nwọn tán, agbara Ọlọ́run bà lé Álmà àti Ámúlẹ́kì, nwọ́n sì dìde dúró lórí ẹsẹ̀ nwọn. Álmà sì kígbe, wípé: Báwo ni yíò ti pẹ́ tó tí àwa yíò faradà ìyà nlá yĩ, Á! Olúwa? Á! Olúwa, fún wa ní agbára gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wa èyítí ó wà nínú Krístì, àní sí ìdásílẹ̀. Nwọn sì já àwọn okùn tí nwọ́n fi dè nwọ́n; nígbàtí àwọn ènìyàn nã sì rí èyí, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sĩ sálọ, nítorípé ẹ̀rù ìparun ti dé bá nwọn. Ó sì ṣe tí ẹ̀rù nwọn pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, tí nwọ́n sì ṣubú lulẹ̀, tí nwọn kò lè dé ẹnu ọ̀nà ìta túbú nã; ilẹ̀ nã sì mì tìtì púpọ̀púpọ̀, àwọn ògiri túbú nã sì ya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀, tí nwọ́n sì wó lulẹ̀; adájọ́ àgbà, àti àwọn agbẹjọ́rò, àti àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni, tí nwọ́n na Álmà àti Ámúlẹ́kì sì kú nípa wíwólulẹ̀ nwọn. Álmà àti Ámúlẹ́kì sì jáde kúrò nínú túbú, nwọn kò sì farapa; nítorítí Olúwa ti fún nwọn ní agbára, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nwọn tí ó wà nínú Krístì. Lọ́gán, nwọ́n sì jáde kúrò nínú túbú; a sì tú nwọn sílẹ̀ kúrò nínú ìdè nwọn; túbú sì ti wó lulẹ̀, gbogbo ènìyàn tí ósì wà ní agbègbè ògiri túbú nã, àfi Álmà pẹ̀lú Ámúlẹ́kì, ni a pa; nwọ́n sì jáde lọ́gán lọ sínú ilú nã. Nísisìyí, nígbàtí àwọn ènìyàn gbọ́ ariwo ìró nlá, nwọ́n sáré wa, pẹ̀lú ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn láti mọ́ ìdí èyí; nígbàtí nwọ́n sì rí Álmà àti Ámúlẹ́kì tí nwọn njáde bọ̀wá láti inú túbú, tí ògiri rẹ̀ ti wó lulẹ̀, ẹ̀rù bà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀, nwọn sì sá kúrò níwájú Álmà àti Ámúlẹ́kì àní bí ewúrẹ́ yíò ṣe sá pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ fún kìnìún méjì; báyĩ ni nwọ́n ṣe sá kúrò níwájú Álmà àti Ámúlẹ́kì. 15 Álmà àti Ámúlẹ́kì lọ sí Sídómù, nwọ́n sì dá ìjọ-Ọlọ́run sílẹ̀—Álmà wo Sísrọ́mù sàn, ẹnití ó sì darapọ̀ mọ́ ìjọ-Ọlọ́run—Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ṣe ìrìbọmi fún, ìjọ Ọlọ́run sì ní ìlọsíwájú—Álmà àti Ámúlẹ́kì lọ sí Sarahẹ́múlà. Ní ìwọ̀n ọdún 81 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí a paá laṣẹ fún Álmà àti Ámúlẹ́kì lati jáde ní ìlú nã; nwọ́n sì jáde, nwọ́n sì wá sínú ilẹ̀ Sídómù; sì kíyèsĩ, níbẹ̀ ni nwọ́n ti rí àwọn ènìyàn tí nwọ́n ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Amonáíhà, tí nwọ́n ti lé jáde tí nwọ́n sì sọ ní ókúta, nítorípé nwọ́n gba ọ̀rọ̀ Álmà gbọ́. Nwọ́n sì sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìyàwó àti ọmọ nwọn fún nwọn, àti nípa ara nwọn nã pẹ̀lú, àti nípa ti agbára ìdásílẹ̀ lórí nwọn. Sísrọ́mù dùbúlẹ̀ lórí àìsàn ní Sídómù, pẹ̀lú akọ ibà, èyítí ó rí bẹ̃ nípasẹ̀ ìbànújẹ́ ọkàn an rẹ̀ nítorí ìwà búburú rẹ̀, nítorípé òun rò pé Álmà àti Ámúlẹ́kì kò sí lãyè mọ́; òun sì rò pé a ti pa nwọ́n nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ òun. Ẹ̀ṣẹ̀ nla yĩ, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ míràn sì gbọgbẹ́ lọ́kàn rẹ̀ títí ó fi njẹ̀rora,nítorítí kò ní ìdásílẹ̀, nítorínã, akọ ooru sì bẹ̀rẹ̀ síí jo. Nísisìyí, nígbàtí ó ti gbọ́ pé Álmà àti Ámúlẹ́kì wà nínú ilẹ̀ Sídómù, ó bẹ̀rẹ̀sí ní ìgboyà; ó sì rán iṣẹ́ sí nwọn lọ́gán, pé òun fẹ́ kí nwọ́n wá sọ́dọ̀ òun. Ó sì ṣe tí nwọ́n lọ lógán, ní ìgbọràn sí iṣẹ́ èyítí ó rán sí nwọn; nwọ́n sì wọ inú ilé Sísrọ́mù lọ; nwọ́n sì bã lórí ibùsùn rẹ, nínú àìsàn, tí ó sì wà ní ìdùbúlẹ̀ gan pẹ̀lú akọ ibà; ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ìwà àìṣedẽdé rẹ̀; nígbàtí ó sì rí wọn ó na ọwọ́ rẹ̀ sí wọn, ó sì bẹ̀ nwọ́n pé kí nwọn wo òun sàn. Ó sì ṣe tí Álmà wí fún un, bí ó ṣe mú ọwọ́ rẹ: Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ nínú agbára Krístì sí ìgbàlà bí? Òun sì dahun ó sì wípé: Bẹ̃ni, mo gba gbogbo ọ̀rọ̀ naa tí ẹ̀yin ti kọ́ ni gbọ́. Álmà sì wípé: Bí ìwọ bá gbàgbọ́ nínú ìràpadà Krístì ìwọ lè rí ìwòsàn. Ó sì wípé: Bẹ̃ni, mo gbàgbọ́, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ. Nigbànã ni Álmà kígbe sí Olúwa, wípé: Á!, Olúwa Ọlọ́run wa, ṣãnú fún ọkùnrin yí, kí ó sì wọ́ sàn gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ rẹ̀, èyítí ó wà nínú Krístì. Lehìn tí Álmà ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, Sísrọ́mù fò dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀sí rìn; èyí sì jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu nlá fún gbogbo àwọn ènìyàn nã; ìmọ̀ yĩ sì tàn ká kiri gbogbo ilẹ̀ Sídómù. Álmà sì ṣe ìrìbọmi fún Sísrọ́mù sí ọ̀nà Olúwa; ó sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà nã lọ, láti wãsù sí àwọn ènìyàn nã. Álmà sì fi ìjọ-onígbàgbọ́ kan lọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ Sídómù, ó sì ya àwọn àlùfã sọ́tọ̀, pẹ̀lú àwọn olùkọ́ni ní ilẹ̀ nã, láti ṣe ìrìbọmi fún ẹnìkẹ́ni tí ó bá fẹ́ ṣe ìrìbọmi, sí Olúwa. Ó sì ṣe tí nwọ́n di púpọ̀; nítorítí nwọ́n wá ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti gbogbo agbègbè tí ó yí Sídómù ka, sì rì nwọn bọmi. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Amonáíhà, nwọn ṣì wà nípò ọlọ́kàn-líle àti ọlọ́rùnlíle ènìyàn; nwọn kò sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, tí nwọn sì nwípé agbára èṣù ni Álmà àti Ámúlẹ́kì nlò; nítorítí nwọ́n jẹ́ ipa ti Néhórì, tí nwọn kò sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìrònúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn. Ó sì ṣe, tí Álmà àti Ámúlẹ́kì, lẹ́hìn tí Ámúlẹ́kì ti kẹ̀hìnsí gbogbo wúrà, fàdákà, àti àwọn ọrọ̀ rẹ, èyítí ó wà ní ilẹ̀ Amonáíhà, fún ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nígbàtí àwọn tí nwọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ tẹ́lẹ̀ àti bàbá rẹ̀, àti ìbátan rẹ̀ ti kọ̣́ sílẹ̀; Nítorínã, lẹ́hìn tí Álmà ti fi ìjọ-onígbàgbọ́ lọ́lẹ̀ ní Sídómù, tí òun sì ríi pé ìkìwọ̀ nlá ti wà, àní, tí ó ríi pé àwọn ènìyàn nã ti ki ara nwọn wọ nípa ìgbéraga ní ọkàn nwọn, tí nwọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀sí rẹ ara nwọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, tí nwọn sì nkó ara nwọn jọ ní ibi-mímọ́ nwọn láti sin Ọlọ́run níwájú pẹpẹ, tí nwọn nṣọ́nà tí nwọ́n sì ngbàdúrà nígbà-gbogbo, pe ki nwọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ Sátánì, àti lọ́wọ́ ikú, àti kúrò nínú ìparun— Nísisìyí gẹ́gẹ́bí èmi ti wí, nígbàtí Álmà t i rí gbogbo ohun wọ̀nyí, nítorínã ni ó mú Ámúlẹ́kì, o sì kọjá wá sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà ó sì múu lọ sí ilé tirẹ, tí ó sì gbã níyànjú nínúwàhálà àti ìdánwò rẹ̀, tí ó sì múu lọ́kàn le nínú Olúwa. Báyĩ sì ni ọdún kẹẹ̀wá ìjọba àwọn ọnídàjọ̣́ lórí àwọn ará Nífáì dé òpin. 16 Àwọn ará Lámánì pa àwọn ará Amonáíhà run—Sórámù ṣíwájú àwọn ará Nífáì ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ará Lámánì—Álmà àti Ámúlẹ́kì pẹ̀lú àwọn púpọ̀ míràn wãsù ọ̀rọ̀ nã—Nwọ́n nkọ́ni pé lẹ́hìn àjĩnde rẹ̀, Krístì yíò farahàn sí àwọn ará Nífáì. Ní ìwọ̀n ọdún 81 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe, ní ọdún kọkànlá ti ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Néfía, ní ọjọ́ kãrún oṣù kejì, lẹ́hìn tí àlãfíà púpọ̀ ti wà nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí kò sí ogun tàbí ìjà fún iye ọdún kan, àní títí di ọjọ́ kãrún oṣù kejì ní ọdún kọkànlá, ìró igbe ogun tàn kálẹ̀ jákè-jádò ilẹ̀ nã. Nítori kíyèsĩ, àwọn ọmọ ogun ará Lámánì ti dé sí ìhà aginjù sínú agbègbè ilẹ̀ nã, àní títí dé ìlú nlá Amonáíhà, tí nwọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀sí pa àwọn ènìyàn, tí nwọ́n sì npa ilú nã run. Àti nísisìyí ó sì ṣe, kí àwọn ará Nífáì tó kó ọmọ ogun tí ó pọ̀ tó jọ láti lé nwọn jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã, nwọn ti pa àwọn ènìyàn tí nwọ́n wà nínú ìlú nlá Amonáíhà run, àti pẹ̀lú àwọn tí nwọn wà ní agbègbè etí ìlú Nóà, nwọ́n sì ti kó àwọn míràn ní ìgbèkùn lọ sínú aginjù. Nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ará Nífáì ní ìfẹ́ àti gba àwọn tí nwọ́n ti kó ní ìgbèkùn lọ sínú aginjù padà. Nítorínã, ẹnití nwọ́n ti yàn ní olórí-ológun lórí àwọn ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, (orúkọ rẹ̀ sì ni Sórámù, òun sì ní ọmọọkùnrin méjì Léhì àti Áhà)—nísisìyí Sórámù àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjẽjì, nítorípé nwọn mọ̀ pé Álmà jẹ́ olórí àlùfã ìjọonígbàgbọ́, tí nwọ́n sì ti gbọ́ pé òun ní ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀, nítorínã, nwọ́n tọ̣́ lọ, nwọ́n sì ṣe ìwãdí lọ́wọ́ rẹ̀ láti mọ́ ibití Olúwa fẹ́ kí wọn ó lọ nínú aginjù, láti wá àwọn ará nwọn lọ, àwọn tí àwọn ará Lámánì ti kó ní ìgbèkùn. Ó sì ṣe tí Álmà bẽrè lọ́wọ́ Olúwa nípa ọ̀rọ̀ nã. Álmà sì padà bọ ó sì wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì yíò dá odò Sídónì kọjá ní apá gúsù aginjù, kọjá lọ sápá òkè ìhà agbègbè etí ilú ilẹ̀ Mántì. Sì wọ́, ibẹ̀ ni ẹ̀yin yíò bá nwọn, ní apá ilà oòrùn odò Sídónì, ibẹ̀ ni Olúwa yíò fi àwọn ara yín tí àwọn ará Lámánì ti kó ní ìgbèkùn lée yín lọ́wọ́. Ó sì ṣe tí Sórámù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dá odò Sídónì kọjá, pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun wọn, wọ́n sì kọjá lọ sí ìhà àyíká Mántì, bọ́ sínú aginjù tí ó wà ní ìhà gúsù, èyítí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn Sídónì. Nwọ́n sì kọlũ àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, nwọn sì tú àwọn ará Lámánì ká, nwọ́n sì lé nwọn wọ inú aginjù lọ; nwọ́n sì kó àwọn ará nwọn, tí àwọn ará Lámánì ti kó ní ìgbèkùn, kò sì sí ẹnìkan tí ó ṣègbé nínú àwọn tí nwọ́n kó ní ìgbèkùn.Àwọn arákùnrin nwọn sì kó nwọn wá láti jogún ilẹ̀ nwọn. Báyĩ sì ni ọdún kọkànlá àwọn onídàjọ́ dópin, tí a ti lé àwọn ará Lámánì jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã, tí nwọ́n sì ti pa àwọn ará Amonáíhà run; bẹ̃ni, gbogbo ohun alãyè tí ó jẹ́ ti ará Amonáíhà ni nwọ́n parun, àti ìlú-nlá nwọn, èyítí nwọ́n ti sọ pé Ọlọ́run kò lè parun, nítorí títóbi rẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ní ọjọ́ kanṣoṣo ni ó di ahoro; tí àwọn òkú ènìyàn sì di ìjẹ fún àwọn ajá àti ẹranko ìgbẹ́ ní aginjù. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, lẹ́hìn ọjọ́ pípẹ́, a kó àwọn òkú wọn yí jọ papọ̀ lórí ilẹ̀, nwọ́n sì bò nwọ́n fẹ́rẹ́fẹ́rẹ́. Àti nísisìyí ọ́rùn tí ó njáde láti ibẹ̀ pọ̀ tó bẹ̃ tí àwọn ènìyàn kò lè wọ inú ilẹ̀ Amonáíhà fún ìjogún fún ọdún pípẹ́. A sì pẽ ní Ibi-Ahoro ti àwọn Néhórì; nítorípé àwọn tí a pa jẹ́ ti ipa ti Néhọ́rì; gbogbo ilẹ̀ nwọn sì wà ní ahoro síbẹ̀. Àwọn ará Lámánì kò sì padà bọ̀ wá jagun pẹ̀lú àwọn ará Nífáì mọ́ títí di ọdún kẹrìnlá ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ará Nífáì. Báyĩ sì ni ó rí fún ọdún mẹ́ta tí àwọn ará Nífáì ní àlãfíà lórí ilẹ̀ nwọn gbogbo. Álmà àti Ámúlẹ́kì sì jáde lọ, tí nwọ́n nwãsù ìrònúpìwàdà sí àwọn ènìyàn nã nínú tẹ́mpìlì nwọn, àti nínú ibi-mímọ́ nwọn, àti pẹ̀lú nínú sínágọ́gù nwọn, àwọn èyítí nwọ́n kọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìṣe àwọn Jũ. Gbogbo àwọn tí nwọn yíò bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ nwọn, ni nwọ́n sì fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, ní àìṣe ojúṣãjú ènìyàn, títí lọ. Báyĩ sì ni Álmà àti Ámúlẹ́kì jáde lọ, àti àwọn míràn pẹ̀lú tí a ti yàn fún iṣẹ́ nã, láti wãsù ọ̀rọ̀ nã jákè-jádò ilẹ̀ nã. Ìdásílẹ̀ ìjọ-onígbàgbọ́ nã sì kárí gbogbo ilẹ̀ nã ní gbogbo agbègbè tí ó yíká kiri, lãrín gbogbo àwọn ará Nífáì. Kò sì sí àìdọ́gba lãrín nwọn; Olúwa sì da Ẹ̀mí rẹ̀ sí órí gbogbo ilẹ̀ nã láti palẹ̀ ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn mọ́, tàbí láti palẹ̀ ọkàn nwọn mọ́ láti gba ọ̀rọ̀ nã èyítí yíò kọ́ nwọn nígbàtí yíò bá dé— Pé kí nwọ́n ó máṣe sé ọkàn le sí ọ̀rọ̀-nã, kí nwọ́n máṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́, kí nwọ́n sì lọ sínú ìparun, ṣùgbọ́n pé kí nwọ́n lè gba ọ̀rọ̀-nã pẹ̀lú ayọ̀, àti pé bí ẹ̀ká, kí nwọ́n di lílọ sínú ara àjàrà òtítọ́, tí nwọn yíò sì bọ́ sínú ìsinmi Olúwa Ọlọ́run nwọn. Nísisìyí, àwọn àlùfã nnì tí nwọ́n ti kọjá lọ sí ãrin àwọn ènìyàn nã nwãsù tako gbogbo irọ́-pípa, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti ìlara, àti ìjà, àti àrankàn, àti ìpẹ̀gàn, àti olè jíjà, ìfi ipá jalè, ìkógun, ìpànìyàn, híhu ìwà àgbèrè, àti onírurú ìwà ìfẹ́kúfẹ̃, tí nwọn sì nkígbe pé àwọn ohun wọ̀nyí kò gbọ́dọ̀ rí bẹ̃— Tí nwọ́n sì nkéde àwọn ohun tí ó fẹ́rẹ̀ dé; bẹ̃ni, tí nwọn nkéde bíbọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, ìjìyà àti ikú rẹ̀, àti àjĩnde òkú. Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn nã sì nbẽrè nípa ibití Ọmọ Ọlọ́run nã yíò ti wá; a sì kọ́ nwọn pé òun yíò farahàn nwọ́n lẹ́hìn àjĩnde rẹ̀; eleyĩ ni àwọn ènìyàn nã sì gbọ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ayọ̀ àti inúdídùn. Àti nísisìyí, lẹ́hìn tí a ti fi ìjọ nã lélẹ̀ jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã—tí ó sì ti gba ìṣẹ́gun lórí èṣù, tí a sì nwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní pípé rẹ̀nínú ilẹ̀ nã gbogbo, tí Olúwa sì nda ìbùkún rẹ̀ sí órí àwọn ènìyàn nã—báyĩ ni ọdún kẹrìnlá ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dé òpin. Ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ Mòsíà, tí nwọ́n kọ̀ ẹ̀tọ́ nwọn sí ìjọba, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí nwọ́n sì lọ sí ilẹ̀ Nífáì láti wãsù sí àwọn ará Lámánì ìjìyà nwọn àti ìtúsílẹ̀ nwọn—gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ èyítí Álmà ṣe. 17 Àwọn ọmọ Mòsíà ní ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀, àti ti ìfihàn—Nwọ́n nlọ kãkiri láti kéde ọ̀rọ̀ nã fún àwọn ará Lámánì—Ámọ́nì lọ sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, ó sì di ọmọ-ọ̀dọ̀ Ọba Lámónì—Ámọ́nì kó àwọn agbo ẹran ọba yọ nínú ewu, ó sì pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ ní etí odò Sébúsì. Ẹsẹ 1 sí 3, jẹ́ ní ìwọ̀n ọdún 77 kí a tó bí Olúwa wa; ẹsẹ 4 jẹ́ ní ìwọ̀n ọdún 91 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa; ẹsẹ 5 sí 39 sì jẹ́ ní ìwọ̀n ọdún 91 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Álmà nrin ìrìn-àjò láti ilẹ̀ Gídéónì lọ sí ìhà gúsù, lọ sí ilẹ̀ Mántì, sa wọ́, sí ìyàlẹ́nu rẹ, ó bá àwọn ọmọ Mòsíà pàdé tí nwọ́n nrin ìrìn-àjò lọ sí ìhà ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Nísisìyí, àwọn ọmọ Mòsíà wọ̀nyí wà pẹ̀lú Álmà ní àkokò tí ángẹ́lì kọ́kọ́ yọ sí i; nítorínã, Álmà yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti rí àwọn arákùnrin rẹ̀; èyítí ó sì fi kún ayọ̀ rẹ̀ ni pé nwọ́n ṣì jẹ́ arákùnrin rẹ̀ nínú Olúwa; bẹ̃ni, nwọ́n sì ti di alágbára nínú ìmọ̀ òtítọ́; nítorítí nwọ́n jẹ́ ẹnití ó ní ìmọ̀ tí ó jinlẹ̀, nwọ́n sì ti wá inú ìwé-mímọ́ láìsimi, kí nwọ́n lè mọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n èyí nìkan kọ́; nwọn ti fi ara nwọn fún ọ̀pọ̀ àdúrà, àti ãwẹ̀; nítorínã nwọ́n ní ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti ẹ̀mí ìfihàn, tí nwọ́n bá sì kọ́ni, nwọ́n nkọ́ni pẹ̀lú agbára àti àṣẹ Ọlọ́run. Nwọ́n sì ti nkọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ìwọ̀n ọdún mẹ́rìnlá lãrín àwọn ará Lámánì, tí nwọ́n sì ti ṣe àṣeyọrí púpọ̀ nípa mímú ọ̀pọ̀ wá sí ìmọ̀ òtítọ́; bẹ̃ni, nípa agbára ọ̀rọ̀ nwọn, a mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá síwájú pẹpẹ Ọlọ́run, láti képe orúkọ rẹ, kí nwọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nwọn níwájú rẹ̀. Nísisìyí, àwọn ohun wọ̀nyí ni nwọ́n rí nínú ìrìnàjò nwọn, nítorítí nwọ́n rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú; nwọ́n sì jìyà lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti ara àti ti ọkàn, bí ebi, òùngbẹ àti ãrẹ̀, pẹ̀lú ìyọ́nú nínú ẹ̀mí. Nísisìyí èyí ni àwọn ìrìnàjò nwọn; lẹ́hìn tí nwọ́n ti dágbére fún bàbá nwọn, Mòsíà, ní ọdún kíni àwọn onídàjọ́; lẹ́hìn tí nwọn ti kọ ìjọba ti bàbá nwọn fẹ́ gbé lé nwọn lọ́wọ́, èyí tí ó sì jẹ́ èrò àwọn ènìyàn; Bíótilẹ̀ríbẹ̃ nwọ́n lọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nwọn sì mú idà nwọn, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ nwọn, àti ọrun nwọn, àti ọfà nwọn, àti kànnà-kànnà nwọn, èyí ni nwọ́n ṣe kí nwọ́n lè pèsè oúnjẹ fún ara nwọn nínú aginjù. Báyĩ sì ni nwọ́n kọjá lọ sínú aginjù pẹ̀lú iye awọn tí nwọ́n ti yàn, láti lọ sí ilẹ̀ Nífáì, lati wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí nwọ́n rin ìrìnàjò fún ọjọ́ pípẹ́ nínú aginjù, tí nwọ́n sì gbãwẹ̀ pẹ̀lú àdúrà púpọ̀ pé kí Olúwa kí ó fún nwọn ní Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ kí ó bá nwọn lọ, kí ó sì gbé pẹ̀lú nwọn, kí nwọ́n lè jẹ ohun èlò lọ́wọ́ Ọlọ́run láti mú àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì, tí ó bá leè rí bẹ̃, bọ́ sí inú ìmọ̀ otítọ́, sí inú ìmọ̀ àṣà àìpé àwọn bàbá nwọn, èyítí kò tọ̀nà. Ó sì ṣe tí Olúwa bẹ̀ nwọ́n wò pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀, tí ó sì wí fún nwọn pé: Ẹ gba ìtùnú. A sì tù wọ́n nínú. Olúwa sì wí fún nwọn pẹ̀lú pé: Ẹ lọ sí ãrin àwọn ará Lámánì, àwọn arákùnrin yín, kí ẹ sì gbé ọ̀rọ̀ mi kalẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin níláti ní ìlọ́ra nínú ìpamọ́ra àti ìpọ́njú, kí ẹ̀yin lè jẹ́ àpẹrẹ rere fún nwọn nínú mi, èmi yíò sì ṣe yín ní ohun èlò ní ọwọ́ mi sí ìgbàlà ọkàn púpọ̀. Ó sì ṣe tí ọkàn àwọn ọmọ Mòsíà pẹ̀lú àwọn tí ó wà pẹ̀lú nwọn, ní ìgboyà láti tọ àwọn ará Lámánì lọ láti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún nwọn. Ó sì ṣe nígbàtí nwọn dé agbègbè etí ìlú ilẹ̀ àwọn ará Lámánì, nwọ́n pín ara nwọn sí ọ̀tọ̣́tọ̀, nwọ́n sì pínyà kúrò lọ́dọ̀ ara nwọn, tí nwọ́n sì ní ìrètí nínú Olúwa pé nwọn yíò tun pàdé lẹ́hìn ìkórè nwọn; nítorítí nwọ́n mọ̀ wípé títóbi ni iṣẹ́ tí àwọn ti dáwọ́lé íṣe. Àti pé dájúdájú, títóbi sì nií ṣe, nítorítí nwọn ti dawọ́lé ìwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn tí ó le, tí nwọ́n sì rorò; àwọn ènìyàn tí nwọ́n dunnú sí pípa àwọn ará Nífáì, àti jíjà nwọn ní ólè àti ṣíṣe ìkógun nwọn; ọkàn nwọn sì wà nínú ọrọ̀, tàbí nínú wúrà àti fàdákà, àti òkúta oníyebíye; síbẹ̀ nwọn a máa wá ọ̀nà àti gba ohun wọ̀nyí nípa ìpànìyàn àti ìkógun, kí nwọ́n má bã ṣiṣẹ́ fún nwọn pẹ̀lú ọwọ́ nwọn. Báyĩ ni nwọ́n sì jẹ́ ọ̀lẹ ènìyàn, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nwọn a sì máa bọ òrìṣà, tí ẹ̀gún Ọlọ́run ti bà lé nwọn lórí nítorí àṣà àwọn bàbá nwọn; l’áìṣírò, ìlérí Olúwa wà fún nwọn bí nwọ́n bá rònúpìwàdà. Nítorínã èyí ni ìdí tí àwọn ọmọ Mòsíà ṣe dáwọ́lé iṣẹ́ nã, pé bóyá nwọn yíò mú nwọn wá sí ìrònúpìwàdà; pé bóyá nwọ́n ó mú nwọn mọ́ ìlànà ìràpadà. Nítorínã nwọ́n yára nwọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ ara nwọn, nwọ́n sì kọjá lọ sí ãrin nwọn, olúkúlùkù lọ́tọ̀, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ àti agbára Ọlọ́run tí a ti fún un. Nísisìyí nítorítí Ámọ́nì jẹ́ olórí lãrín nwọn, tàbí pé òun ni ó ntọ́ nwọn sọ́nà, ó kúrò lãrín nwọn lẹ́hìn tí ó ti súre fún nwọn gẹ́gẹ́bí ipò àti ipè olúkúlùkù, lẹ́hìn tí ó ti kọ́ nwọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tàbí tí ó ti tọ́ nwọn sọ́nà, kí ó tó kọjá lọ kúrò; báyĩ ni nwọ́n sì lọ sí ìrìnàjò nwọn jákè-jádò ilẹ̀ nã. Ámọ́nì sì lọ sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, ilẹ̀ èyítí a pe ní órúkọ àwọn ọmọ ọkùnrin Íṣmáẹ́lì, tí nwọ́n ti di ara àwọn ará Lámánì. Bí Ámọ́nì sì ṣe wọ inú ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, àwọn ará Lámánì múu, nwọ́n sì dẽ, ní ìbámu pẹ̀lú àṣà nwọn láti de gbogbo ará Nífáì tí ó bá bọ́ sí nwọn lọ́wọ́, tí nwọn ó sì gbé nwọn lọ síwájú ọba; bayi ni yio sì jẹ ìdùnnú oba latipa wọn, tabi ki o fi wọn sílẹ̀ ninu ìgbèkùn, tabi kí o gbé wọn si inú túbú, tabi ki o le wọn jáde kuro nínú ìlẹ̀ rẹ̀; gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ ati ìdùnnú rẹ̀. Báyĩ sì ni nwọn gbé Ámọ́nì lọ siwaju ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì; t í orúkọ rẹ̀ sì íṣe Lámónì; ọmọ àtẹ̀lé Íṣmáẹ́lì nií sĩ ṣe. Ọba nã sì bẽrè lọ́wọ́ Ámọ́nì bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ inúu rẹ̀ láti gbé inú ìlú nã lãrín àwọn ará Lámánì, tàbí lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀. Ámọ́nì sì wí fún un pé: Bẹ̃ni, mo fẹ́ láti gbé lãrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí fún àkokò díẹ̀; bẹ̃ni, bóyá títí ọjọ́ ikú mi. Ó sì ṣe tí inú ọba Lámónì dùn púpọ̀ sí Ámọ́nì, tí ó sì ní kí nwọ́n tú ìdè rẹ̀; tí ó sì fẹ́ kí Ámọ́nì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ṣe aya. Ṣùgbọ́n Ámọ́nì wí fún un pé: Rárá, ṣùgbọ́n èmi yíò jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ. Nítorínã Ámọ́nì di ọmọ-ọ̀dọ̀ fún Lámónì ọba. Ó sì ṣe tí a fi sí ãrin àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ yókù láti ṣọ́ àwọn agbo ẹran Lámónì, gẹ́gẹ́bí àṣà àwọn ará Lámánì. Nígbàtí ó sì ti nṣiṣẹ́-ìsìn fún ọba fún ọjọ́ mẹ́ta, bí ó sì ti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ Lámónì tí wọ́n jẹ́ ará Lámánì, tí nwọn nlọ pẹ̀lú agbo-ẹran nwọn sí ibi omi, èyítí à npè ní omi Sébúsì, gbogbo àwọn ará Lámánì nã ni nwọn a sì máa da agbo ẹran nwọn wá síbẹ̀, kí nwọ́n lè mumi. Nítorínã, bí Ámọ́nì pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ọba ti nda agbo ẹran nwọn lọ sí ibi omi yìi, wòo, àwọn ará Lámánì kan, tí nwọ́n ti wà pẹ̀lú agbo ẹran nwọn láti fún nwọn lómi, dúró, nwọ́n sì tú àwọn agbo ẹran Ámọ́nì àti ti àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọba ká, nwọ́n sì tú nwọn ká tó bẹ́ẹ̀ tí nwọ́n fi sá kãkiri ọ̀nà púpọ̀. Nísisìyí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọba bẹ̀rẹ̀sí ráhùn wípé: Ní báyĩ ọba yíò pa wá, gẹ́gẹ́bí ó ti ṣe pa àwọn arákùnrin wa, nígbàtí àwọn ẹni búburú wọ̀nyí tú agbo-ẹran nwọn ká. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sọkún púpọ̀púpọ̀, nwọ́n nwípé: Wọ́, gbogbo agbo-ẹran wa ni nwọ́n ti túká. Báyĩ nwọ́n sọkún nítorí ìbẹ̀rù pé a ó pa nwọ́n. Bí Ámọ́nì ṣe rí èyí ọkàn an rẹ̀ kún fún ayọ̀ nínũ rẹ̀; nítorítí, ó wípé, èmi yíò fi agbára mi han àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ mi, tàbí agbára èyítí nbẹ nínú mi, fún ìdápadà àwọn agbo-ẹran wọ̀nyí sí ọ́dọ̀ ọba, kí èmi kí ó lè rí ojú-rere àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹlẹ́gbẹ́ mi, kí èmi kí ó lè tọ́ nwọn sọ́nà gbígba ọ̀rọ̀ mi gbọ́. Àti nísisìyí, àwọn yìi ni èrò ọkàn Ámọ́nì, nígbàtí ó rí ìjìyà àwọn tí ó pè ní arákùnrin rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó sọ̀rọ̀ ìṣírí sí nwọn, tí ó wípé: Ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ tújúká kí ẹ sì jẹ́ kí àwa kí ó wá àwọn agbo-ẹran wa lọ, àwa yíò sì gba nwọn jọ, a ó sì kó nwọn padà wá sí ibi omi; báyĩ àwa yíò pa àwọn agbo-ẹran nã mọ́ fún ọba, òun kò sì ní pa wá. Ó sì ṣe tí nwọ́n wá àwọn agbo-ẹran nã lọ, nwọ́n sì tẹ̀lé Ámọ́nì, nwọ́n sì sáré síwájú kánkán, ṣãju àwọn agbo-ẹran ọba, nwọ́n sì tún kó nwọn jọ lọ sí ibi omi. Àwọn ọkùnrin nã tún dúró láti tú agbo-ẹran nwọn ká;ṣùgbọ́n Ámọ́nì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: Ẹ pagbo yí àwọn agbo-ẹran nã ká, kí nwọn má lè sálọ; èmi yíò sì lọ dojú ìjà kọ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí nwọn ntú àwọn agbo-ẹran wa ká. Nítorínã, nwọ́n ṣe gẹ́gẹ́bí Ámọ́nì ṣe pàṣẹ fún nwọn, ó sì lọ ó dúró láti dojú ìjà kọ àwọn tí ó dúró ní ẹ̀bá omi Sébúsì; iye nwọn kò sì kéré rárá. Nítorínã nwọn kò bẹ̀rù Ámọ́nì, nítorítí nwọ́n rò pé ọkàn nínú nwọn lè pa ní ìrọ̀rùn, nítorípé nwọn kò mọ̀ pé Olúwa ti ṣèlérí pẹ̀lú Mòsíà pé òun yíò yọ àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ nwọn; bẹ̃ sì ni nwọn kò mọ́ ohunkóhun nípa Olúwa; nítorínã ni nwọ́n ṣe nyọ̀ nínú ìparun àwọn arákùnrin nwọn; nítorí ìdí èyí ni nwọ́n ṣe dúró láti tú agbo-ẹran ọba ká. Ṣùgbọ́n Ámọ́nì dúró lókẽrè, ó sì bẹ̀rẹ̀sí sọ òkò sí nwọn pẹ̀lú kànnà-kànnà rẹ̀; bẹ̃ni, pẹ̀lú agbára nlá ni ó fi sọ òkò sí ãrin nwọn; bẹ̃ni ó sì pa nínú nwọn tó bẹ̃ tí ẹnu bẹ̀rẹ̀sí yà nwọ́n nípa agbára rẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃ inú bí nwọn nítorí àwọn arákùnrin nwọn tí ó ti pa, tí nwọ́n sì pinnu pé nwọn yíò ṣẹ́gun nwọn; nígbàtí nwọn sì ríi pé òkò nwọn kò bã, nwọ́n wá pẹ̀lú kùmọ̀ láti fi paá. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, gbogbo ẹnití ó gbé kùmọ̀ sókè láti lu Ámọ́nì, ni ó gé apá rẹ kúrò pẹ̀lú idà rẹ; nítorítí ó tako lílù nwọ́n nípa gígé apá nwọn pẹ̀lú idà rẹ̀, tó bẹ̃ tí ẹnu bẹ̀rẹ̀sí yà nwọ́n, tí nwọ́n sì sálọ kúrò níwájú rẹ̀; bẹ̃ni, nwọn kò sì mọ́ díẹ̀ ní iye rárá; ó sì lé nwọn sá nípa agbára ọwọ́ rẹ. Nísisìyí, àwọn mẹ́fà nínú nwọn ni ó ti ṣubú nípa kànnàkànnà nã, ṣùgbọ́n kò pa ọ̀kan nínú nwọn, àfi olórí nwọn pẹ̀lú idà rẹ; ó sì gé apá gbogbo àwọn tí nwọ́n kọlũ kúrò, nwọn kò sì mọ́ ní díẹ̀ rárá. Nígbàtí ó sì ti lé nwọn jìnà réré, ó padà nwọ́n sì fún àwọn agbo-ẹran nwọn lómi, nwọ́n sì dá nwọn padà sínú pápá oko ọba, nwọ́n sì tọ ọba lọ, pẹ̀lú àwọn apá tí idà Ámọ́nì ti gé kúrò, tí àwọn tí nwọ́n fẹ́ paa; nwọ́n sì gbé nwọn tọ ọba lọ fún ẹ̀rí ohun tí nwọ́n ti ṣe. 18 Ọba Lámónì rò wípé Ámọ́nì ni Òrìṣà Nlá nã—Ámọ́nì kọ́ ọba nã ní ẹ̀kọ́ nípa ìdásílẹ̀ ayé, nípa bí Ọlọ́run ṣe nbá ènìyàn lò, àti nípa ìràpadà tí ó wá nípasẹ̀ Krístì—Lámónì gbàgbọ́ ó sì ṣubú lulẹ̀ bí ẹnití ó ti kú. Ní ìwọ̀n ọdún 90 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí ọba Lámónì pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ kọjá síwájú kí nwọ́n sì jẹ́rĩ sí gbogbo ohun tí nwọ́n ti rí nípa ọ̀rọ̀ nã. Nígbàtí gbogbo nwọ́n sì ti jẹ́rĩ sí gbogbo ohun tí nwọ́n ti rí, tí òun sì ti gbọ́ nípa ìwà òtítọ́ Ámọ́nì bí ó ti pa agbo-ẹran rẹ̀ mọ́, àti nípa agbára rẹ̀ tí ó fi bá àwọn tí nwọ́n fẹ́ paá jà, ẹnu yã lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì wípé: Nítoótọ́, eleyĩ kĩ ṣe ènìyàn lásán. Kíyèsĩ, njẹ́ kĩ ha íṣe Òrìṣà Nlá nnì tí ó bẹ àwọn ènìyàn yĩ wò pẹ̀lú ìyà nítorí ìpànìyàn nwọn? Nwọ́n sì dá ọba lóhùn, nwọn wípé: Yálá Òrìṣà Nlá nnì nií ṣe tàbí ènìyàn, àwa kò mọ̀; ṣùgbọ́n,èyí ni àwa mọ̀, pé àwọn ọ̀tá ọba kò lè paá; bẹ̃ sì ni nwọn kò lè tú àwọn agbo-ẹran ọba ká nígbàtí ó wà pẹ̀lú wa, nítorí ìmọ̀ rẹ̀ àti agbára nlá rẹ̀; nítorínã, àwa mọ̀ wípé ọ̀rẹ́ ọba nií ṣe. Àti nísisìyí Á! ọba, àwa kò gbàgbọ́ pé ènìyàn kan lè ní irú agbára nlá bẹ̃, nítorítí àwa mọ̀ pé nwọn kò lè paá. Àti nísisìyí, nígbàtí ọba nã gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó wí fún nwọn pé: Báyĩ èmi mọ̀ wípé Òrìṣà Nlá nnì ni íṣe; òun sì ti sọ̀kalẹ̀ wá ní àkókò yí láti pa ẹ̀mí yín mọ́, kí èmi kí ó má bã pa yín gẹ́gẹ́bí èmi ṣe pa àwọn arákùnrin yín. Nísisìyí, èyí ni Òrìṣà Nlá nã, èyítí àwọn bàbá wa ti sọ nípa rẹ̀. Nísisìyí èyí sì ni àṣà èyítí Lámónì ti gbà láti ọwọ́ bàbá rẹ̀, wípé Òrìṣà Nlá kan wà. L’áìṣírò nwọ́n gbàgbọ́ nínú Òrìṣà Nlá kan, tí nwọ́n sì lérò pé ohunkóhun tí nwọ́n bá ṣe ni ó dára; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Lámónì bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀rù gidigidi, pẹ̀lú ìbẹ̀rù pé bóyá òun ti kùnà nínú pipa àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ òun; Nítorítí ó ti pa púpọ̀ nínú nwọn nígbàtí àwọn arákùnrin nwọn tú agbo-ẹran nwọn ká ní ìdí odò; tí ó sì jẹ́ wípé bí nwọ́n ṣe tú agbo-ẹran nwọn ká nnì, a ti pa nwọ́n. Nísisìyí, ó jẹ́ àṣà àwọn ará Lámánì láti dúró sí ìdí odò Sébúsì láti tú agbo-ẹran àwọn ènìyàn nã ká, nípasẹ̀ èyítí nwọn yíò lé púpọ̀ àwọn tí nwọ́n túká lọ sí orí ilẹ̀ tiwọn, èyítí íṣe ìwà ìkógun lãrín nwọn. Ó sì ṣe tí ọba Lámónì bẽrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: Níbo ni ọkùnrin yí tí ó ní irú agbára nlá nã wà? Nwọ́n sì wí fún pé: Kíyèsĩ, ó nfún àwọn ẹṣin rẹ ní óúnjẹ. Báyĩ ṣãju àkokò yí tí nwọ́n nfún àwọn agbo-ẹran ni ómi, ọba ti pàṣẹ pé kí nwọ́n pèsè àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sílẹ̀, kí nwọ́n sì gbé òun yí ilẹ̀ Nífáì ká, nítorítí bàbá Lámónì tí íṣe ọba lórí ilẹ̀ nã gbogbo ti pèsè àpèjẹ kan ní ilẹ̀ Nífáì. Nísisìyí, nígbàtí ọba Lámónì gbọ́ wípé Ámọ́nì npèsè àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sílẹ̀, ẹnu túbọ̀ yã sí, nítorí ìṣòdodo Ámọ́nì, ó sì wípé: Dájúdájú kò tĩ sí ọmọ-ọ̀dọ̀ kan lãrín gbogbo ọmọ-ọ̀dọ̀ mi tí ó jẹ́ olọ́tọ́ bí ọkùnrin yí; nítorítí ó tún rántí gbogbo àṣẹ tí mo pa kí òun lè ṣe nwọ́n. Nísisìyí, èmi mọ̀ dájú pé Òrìṣà Nlá nã ni èyí, èmi sì ní ìfẹ́ sí pé kí ó wá sí iwájú mi, ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ ṣe bẹ̃. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ámọ́nì ti pèsè àwọn ẹṣin pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọba sílẹ̀ tán; ó tọ ọba lọ, ó sì ríi pé ojú ọba ti yí padà; nítorínã, ó fẹ́ padà kúrò níwájú rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọba sì sọ fún un wípé: Rábbánà, èyítí ó túmọ̀ sí, ọba alágbára tàbí ọba nlá, nítorítí nwọ́n ka àwọn ọba nwọn sí alágbára; báyĩ ni ó sì wí fún un: Rábbánà, ọba fẹ́ kí ìwọ kí ó dúró. Nítorínã, Ámọ́nì yípadà sí ọ̀dọ̀ ọba, ó sì wí fún un pé: Kíni ìwọ fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún ọ, A! ọba? Ọba kò sì dáa lóhùn fún ìwọ̀n wákàtí kan, gẹ́gẹ́bí ìṣirò àkókò tiwọn, nítorítí kò mọ́ ohun tí òun yíò sọ fún ún. Ó sì ṣe tí Ámọ́nì tún wí fún un pé: Kíni ìwọ fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún ọ? Ṣùgbọ́n ọba kò fèsì fún un. Ó sì ṣe, tí Ámọ́nì, nítorítí ó kún fún Ẹ̀mí Ọlọ́run, nígbànã ni ó mọ́ èrò ọkàn ọba. Ó sì wí fún un pé: Ṣé nítorítí ìwọ ti gbọ́ pé èmi dãbò bò àwọn agbo-ẹran rẹ, tí èmi sì pa méje nínú àwọn arákùnrin nwọn pẹ̀lú kànnàkànnà àti idà, tí èmi sì gé apá àwọn yókù, láti lè dãbò bò àwọn agbo-ẹran rẹ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ; wọ́, njẹ́ èyí ni ó ha fa ìyàlẹ́nu fún ọ? Èmi wí fún ọ, kíni ìdí rẹ̀ tí ìyàlẹ́nu rẹ fi tó èyí? Wọ́, ènìyàn ni èmi íṣe, ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ sì ni èmi; nítorínã, ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ tí ó tọ̀nà, òun nã ni èmi yíò ṣe. Nísisìyí nígbàtí ọba ti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ẹnu tún yã sĩ, nítorítí ó rĩ pé Ámọ́nì lè mọ àwọn èrò ọkàn òun; ṣùgbọ́n l’áìṣírò eyi, ọba Lámónì la ẹnu rẹ̀, ó sì wí fún un pé: Tani ìwọ íṣe? Njẹ́ ìwọ ni Òrìṣà Nlá nnì, tí ó mọ ohun gbogbo? Ámọ́nì dáa lóhùn ó sì wí fún un pé: Èmi kọ́. Ọba sì tún wípé: Báwo ni ìwọ ha ṣe mọ́ àwọn èrò ọkàn mi? Ìwọ lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà, kí ó sì sọ nípa àwọn ohun wọ̀nyí fún mi; kí ìwọ sì tún sọ fún mi nípa agbára èyítí ìwọ fi pa àwọn arákùnrin mi, àwọn tí nwọn ntú àwọn agbo-ẹran mi ká, tí ìwọ sì tún gé apá nwọn— Àti nísisìyí, bí ìwọ bá lè sọ fun mí nípa ohun wọ̀nyí, ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́, èmi yíò fún ọ; tí ó bá sì yẹ, èmi yíò ṣọọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun mi; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ìwọ lágbára ju gbogbo nwọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ kí èmi fún ọ, èmi yíò fún ọ. Nísisìyí, Ámọ́nì jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kò sì ní ẹ̀mí ìpanilára, ó wí fún Lámónì: Njẹ́ ìwọ yíò gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí èmi bá sọ fún ọ nípa agbára tí èmi fi nṣe ohun wọ̀nyí? Èyí sì ni ohun tí èmi fẹ́ láti ọwọ́ rẹ. Ọba sì dáa lóhùn, ó sì wí pé: Bẹ̃ni, èmi yíò gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́. Báyĩ sì ni a fi ẹ̀tàn múu. Ámọ́nì sì bẹ̀rẹ̀sí bã sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà, ó sì wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ ha gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan nbẹ? Òun sì dáhùn, ó sì wí fún un pé: Èmi kò mọ́ ìtúmọ̀ èyí nnì. Ámọ́nì sì tún wípé: Njẹ́ ìwọ ha gbàgbọ́ pé Òrìṣà Nlá kan nbẹ? Ó sì wí pé, Bẹ̃ni. Ámọ́nì sì wípé: Èyí yĩ ni Ọlọ́run. Ámọ́nì sì tún wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé Òrìṣà Nlá yìi, tí íṣe Ọlọ́run, ni ó dá ohun gbogbo tí ó wà ní ọ̀run àti ní ayé? Ó sì wí pé: Bẹ̃ni, mo gbàgbọ́ pé òun ni ó dá ohun gbogbo tí ó wà ní ayé; ṣùgbọ́n èmi kò mọ̀ nípa àwọn ọ̀run. Ámọ́nì sì wí fún un pé: Ọ̀run jẹ́ ibi tí Ọlọ́run ngbé ati gbogbo àwọn ángẹ́lì mímọ́ rẹ̀. Ọba Lámónì sì wípé: Ṣe òkè ayé ni ó wà ni? Ámọ́nì sì wípé: Bẹ̃ni, òun a sì máa bojúwò gbogbo àwọn ọmọ ènìyàn nísàlẹ̀; òun sì mọ gbogbo èrò inú ọkàn; nítorítí nípa ọwọ́ rẹ ni a dá nwọn ní àtètèkọ́ṣe. Ọba Lámónì wípé: Mo gba ohun wọ̀nyí gbogbo gbọ́ tí ìwọti sọ. Njẹ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti rán ọ wá? Ámọ́nì wí fún un pé: Ènìyàn ni èmi íṣe; a sì dá ènìyàn ní àtètèkọ́ṣe ní àwòrán Ọlọ́run, a sì pè mí nípa Ẹ̀mí Mímọ́ rè láti kọ́ àwọn ènìyàn yí ní àwọn ohun wọ̀nyí, kí a lè mú wọn wá ìmọ̀ èyítí ó tọ́ tí ó sì jẹ́ òtítọ́; Apákan Ẹ̀mí ná ni sì ngbé inú mi, èyítí ó nfún mi ní ìmọ̀, pẹ̀lú agbára gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ mi àti ìfẹ́ ọkàn mi tí nwọn nbẹ nínú Ọlọ́run. Nísisìyí nigbati Ámọ́nì sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó bẹ̀rẹ̀ láti dídá ayé sílẹ̀, àti dídá Ádámù, ó sì sọ ohun gbogbo fún un nípa ìṣubú ènìyàn, ó sì tún sọọ́ ní yékéyéké, àwọn àkọsílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìwé-mímọ́ àwọn ènìyàn nã, tí àwọn wòlĩ ti sọ nípa nwọn àní títí dé ìgbà tí Léhì bàbá nwọn fi kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Ó sì tún sọọ́ yé nwọn yékéyéké (nítorítí ó ṣe èyí sí ọba àti àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ) gbogbo ìrìnàjò àwọn bàbá nwọn nínú aginjù, àti gbogbo ìpọ́njú nwọn pẹ̀lú ebi àti òùngbẹ, àti ìdãmú nwọn, àti bẹ̃bẹ̃ lọ. Ó sì tún sọọ́ ní yéké fún nwọn nípa ọ̀tẹ̀ Lámánì pẹ̀lú Lẹ́múẹ́lì, àti àwọn ọmọ Íṣmáẹ́lì, bẹ̃ni, gbogbo ìwà ọ̀tẹ̀ nwọn ni ó rò fún nwọn; ó sì ṣe àlàyé fún nwọn lórí àwọn àkọsílẹ̀ àti àwọn ìwé-mímọ́ láti ìgbà tí Léhì jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù, títí dé àkokò yí. Ṣùgbọ́n èyí nìkan kọ́; nítorítí ó ṣe àlàyé nípa ìlànà ìràpadà fún nwọn, èyítí a ti pèsè sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé; òun sì sọ fún nwọn nípa bíbọ̀ Krístì, gbogbo iṣẹ́ Olúwa ni òun sì sọ nípa rẹ̀ fún nwọn. Ó sì ṣe nígbàtí ó ti sọ gbogbo nkan wọ̀nyí tán, tí ó sì ṣe àlàyé lórí nwọn fún ọba, ni ọba sì gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé Olúwa, wípé: Á! Olúwa, ṣãnú; gẹ́gẹ́bí ọ̀pọ̀ ãnú rẹ èyítí ìwọ ti ní fún àwọn ènìyàn Nífáì, ṣãnú fún mi, àti àwọn ènìyàn mi. Àti nísisìyí, nígbàtí ó sọ eleyĩ tán, ó ṣubú lulẹ̀, bí ẹnipé ó ti kú. Ó sì ṣe tí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ múu, tí nwọ́n sì gbée lọ sí ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀, nwọ́n sì gbée sórí ibùsùn kan; òun sì sùn bí ẹnipé ó ti kú fún ìwọ̀n ọjọ́ méjì àti òru méjì; ìyàwó rẹ, àti àwọn ọmọ ọkùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ obìnrin rẹ̀ ṣọ̀fọ̀ rẹ, ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àwọn ará Lámánì; tí nwọ́n sì ndárò lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ikú rẹ. 19 Lámónì rí ìmọ́lẹ̀ ìyè títí ayé gbà, ó sì rí Olùràpadà nã—Agbo ilé rẹ wọ inú ìran lọ, ọ̀pọ̀ sì rí àwọn ángẹ́lì—Olúwa pa Ámọ́nì mọ́ ní ọ̀nà ìyanu—“Ó ṣe rìbọmi fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì dá ìjọ-onígbàgbọ́ sílẹ̀ lãrín nwọn. Ní ìwọ̀n ọdún 90 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe, lẹ́hìn ọjọ́ méjì àti òru méjì, tí nwọn nmúra láti gbée lọ tẹ́ sínú ibojì, èyítí nwọn ti ṣe fún sísin òkú nwọn. Nísisìyí, nítorítí ayaba ti gbọ́ nípa òkìkí Ámọ́nì, nítorínã ó ránṣẹ́ ó sì fẹ́ kí ó tọ òun wá. Ó sì ṣe, tí Ámọ́nì ṣe gẹ́gẹ́bí a ti paláṣẹ fún un; tí ó sì tọ ayaba lọ, tí ó sì bẽrè ohun tí ó fẹ́ kí òun ṣe. Ó sì wí fún un: Àwọn ọmọọ̀dọ̀ ọkọ mi ti sọọ́ di mímọ̀ fún mi pé wòlĩ Ọlọ́run mímọ́ ni ìwọ íṣe, àti pé ìwọ ní agbára láti ṣe iṣẹ́ títóbi tí ó pọ̀ ní orúkọ rẹ̀; Nítorínã, tí ó bá rí báyĩ, èmi fẹ́ kí ìwọ kí ó wọlé lọ wo ọkọ mi, nítorĩ a ti tẹ́ẹ lé orí ibùsùn rẹ̀ fún ìwọ̀n ọjọ́ méjì àti òru méjì; tí àwọn kan sọ wípé kòì kú, ṣùgbọ́n àwọn míràn wípé ó ti kú, ó sì ti nrùn, pé kí nwọ́n gbée lọ sínú ibojì; ṣùgbọ́n ní tèmi, kò rùn sí mi. Nísisìyí, ohun tí Ámọ́nì fẹ́ ni èyí, nítorí tí ó mọ̀ pé ọba Lámónì nbẹ lábẹ́ agbára Ọlọ́run; ó mọ̀ pé ìbòjú dúdú àìgbàgbọ́ ti nká kúrò lọ́kàn rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ tí ó sì tàn sí ọkàn rẹ, èyítí ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ògo Ọlọ́run, èyítí í ṣe ìmọ́lẹ̀ ìyànu dídára rẹ̀—bẹ̃ni, ìmọ́lẹ̀ yí ti fi ọ̀pọ̀ ayọ̀ sínú ọkàn rẹ̀, lẹ́hìn tí ìkũkù òkùnkùn ti ká kúrò, tí ìmọ́lẹ̀ ìyè títí ayé ti tànmọ́lẹ̀ sí ọkàn rẹ, bẹ̃ni, òun mọ̀ pé èyí ti ṣíji bò ara rẹ̀, tí a sì gbée lọ nínú Ọlọ́run— Nítorínã, ohun tí ayaba fẹ́ kí ó ṣe ni ìfẹ́ ọkàn rẹ. Nítorínã, ó wọlé lọ rí ọba gẹ́gẹ́bí ayaba ti fẹ́ kí ó ṣe; ó sì rí ọba nã, ó sì mọ̀ wípé kò kú. Ó sì wí fún ayaba pé: Kò kú, ṣùgbọ́n ó nsùn nínú Ọlọ́run ni, ní ọ̀la òun yíò sì dìde; nítorínã ẹ máṣe sin ín. Ámọ́nì tún wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ gba èyí gbọ́? Òun sì wí fún un pé: Èmi kò ní ẹ̀rí míràn àyàfi ọ̀rọ̀ rẹ, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wa; bíótilẹ̀ríbẹ̃ èmi gbàgbọ́ wípé yíò rí gẹ́gẹ́bí ìwọ ti sọ. Ámọ́nì sì wí fún un pé: Ìbùkún ni fún ọ nítorí ìgbàgbọ́ rẹ tí ó tayọ; mo wí fún ọ, ìwọ obìnrin, a kòĩ tì rí ìgbàgbọ́ nlá irú èyí rí lãrín gbogbo àwọn ará Nífáì. Ó sì ṣe tí ó nṣọ́ ibùsùn ọkọ rẹ̀, láti ìgbà nã lọ títí di àkokò nã ní ọjọ́ kejì tí Ámọ́nì sọ wípé yíò dìde. Ó sì ṣe tí ó sì dìde, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Ámọ́nì; bí ó si ṣe ndìde, ó na ọwọ́ rẹ sí obìnrin nã, ó sì wípé: Ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run, ìbùkún sì ni fún ìwọ nã. Nítorítí bí ó ṣe dájú pé ìwọ wà lãyè, kíyèsĩ, èmi ti rí Olùràpadà mi; òun yíò sì wa, tí a ó bĩ nípasẹ̀ obìnrin, òun yíò sì ra gbogbo ènìyàn padà tí nwọ́n gba orúkọ rẹ̀ gbọ́. Nísisìyí, nígbàtí ó ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ọkàn rẹ̀ wúwo nínú rẹ̀. ó sì tún ṣubú lulẹ̀ lẹ́ẹkan síi pẹ̀lú ayọ̀; ayaba nã sì ṣubú lulẹ̀ pẹ̀lú, nítorítí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣíji bọ́. Nísisìyí, nígbàtí Ámọ́nì ríi pé Ẹ̀mí Olúwa sọ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́bí àdúrà rẹ̀ sí órí àwọn ará Lámánì, àwọn arákùnrin rẹ̀, tí nwọ́n ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀fọ̀ ṣíṣe lãrín àwọn ará Nífáì, tàbí gbogbo àwọn ènìyàn Ọlọ́run nitori àìṣedẽdé nwọn àti àṣà nwọn, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀sí gbàdúrà tọkàn-tọkàn pẹ̀lú ọpẹ́ sí Ọlọ́run fún ohun tí ó ti ṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀; òun nã sì kún fún ayọ̀ púpọ̀púpọ̀; báyĩ sì ni àwọn mẹ́tẹ̃ta wólẹ̀. Nísisìyí, nígbàtí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọba ríi pé nwọ́n ti ṣubú, àwọn nã sì bẹ̀rẹ̀sí kígbe pé Ọlọ́run, nítorípé ìbẹ̀rù Olúwa ti bá àwọn nã, nítorípé àwọn ni nwọ́n dúró níwájú ọba tí nwọn jẹ́rĩ nípa agbára nlá Ámọ́nì. Ó sì ṣe tí nwọ́n kígbe pe orúkọ Olúwa pẹ̀lú gbogbo agbára nwọn, àní títí nwọ́n fi ṣubú lulẹ̀ àfi ọ̀kan nínú àwọn obìnrin Lámání, tí orúkọ rẹ̀ íṣe Ábíṣì, nítorítí a ti yíi lọ́kàn padà sí Olúwa ní ọdún pípẹ́ sẹ́hìn, nípasẹ̀ ìran ìyanu bàbá rẹ̀ kan— Bí ó sì ti jẹ́ wípé ó ti yípadà sọ́dọ̀ Olúwa, tí kò sì jẹ́ kí ẹnìkẹ́ni kí ó mọ̀, nítorínã, nígbàtí ó ríi pé gbogbo àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ Lámónì ti ṣubú lulẹ̀, àti pẹ̀lú pé “ọ̀gá” rẹ, ayaba, àti ọba, àti Ámọ́nì nà gbalaja lé ilẹ̀, ó mọ̀ wípé agbára Ọlọ́run ni; nígbàtí ó sì rọ́ pé tí òun bá jẹ́ kí àwọn ènìyàn nã mọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí nwọn, pé nípa rírí ohun yìi, yíò jẹ́ kí nwọ́n gbàgbọ́ nínú agbára Ọlọ́run, nítorínã ó sáré jáde láti ilé kan dé ìkejì, ó sì nfi tó àwọn ènìyàn létí. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí kó ara nwọn jọ sínú ilé ọba. Ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn sì wá, sí ìyàlẹ́nu nwọn ẹ̀wẹ̀, nwọ́n rí ọba, pẹ̀lú ayaba àti àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ nwọn tí nwọ́n ti nà gbalaja lélẹ̀, tí nwọ́n sì wà níbẹ̀ bí ẹnipé nwọ́n ti kú; nwọ́n sì rí Ámọ́nì pẹ̀lú, sì wọ́, ara Nífáì ni òun íṣe. Àti nísisìyí, àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí ráhùn lãrín ara nwọn; àwọn kan nsọ wípé ìṣẹ̀lẹ̀ búburú kan ni ó ti dé bá nwọn, tàbí bá ọba àti ilé rẹ, nítorítí ó ti jẹ́ kí ará Nífáì nã dúró ní ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n àwọn míràn bá nwọn wí, wípé: Ọba ni ó mú ibi wá sí ilé rẹ nítorípé ó pa àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí nwọn ti tú agbo-ẹran nwọn ká ní ibi omi Sébúsì. Àwọn ọkùnrin tí nwọ́n dúró ní ibi omi Sébúsì tí nwọ́n sì tú agbo-ẹran tĩ ṣe ti ọba ká nã bá nwọn wi nítorípé nwọ́n bínú sí Ámọ́nì nítorí iye àwọn tí ó ti pa nínú àwọn arákùnrin nwọn ní ibi odò Sébúsì, nígbàtí ó ndãbò bò àwọn agbo-ẹran ọba. Nísisìyí, ọ̀kan nínú nwọn, tí a ti fi idà Ámọ́nì pa arákùnrin rẹ̀, nítorítí ó bínú púpọ̀púpọ̀ pẹ̀lú Ámọ́nì, fa idà rẹ yọ, ó sì lọ kí òun lè kọlũ Ámọ́nì, láti pa; bí ó ṣe gbé idà sókè láti bẹ̃, kíyèsĩ, ó wó lulẹ̀ ó sì kú. Nísisìyí, a ríi pé nwọn kò lè pa Ámọ́nì, nítorítí Olúwa ti sọọ́ fún Mòsíà bàbá rẹ̀ pé: Èmi yíò dáa sí, yió sì rí bẹ̃ gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ rẹ—nítorínã, Mòsíà gbẽ lé Olúwa lọ́wọ́. Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn ríi pé ọkùnrin nã ti wó lulẹ̀ tí ó sì kú, ẹnití ó gbé idà sókè láti pa Ámọ́nì, ẹ̀rù bá gbogbo nwọn, nwọn kò sì jẹ́ na ọwọ́ nwọn jáde láti fi ọwọ́ kan an tàbí èyíkẽyí nínú àwọn tí ó ti ṣubú lulẹ̀; ẹnu sì tún bẹ̀rẹ̀sí ya nwọn lãrín ara nwọn pé kíni ó lè jẹ́ ìdí agbára nlá yĩ, tàbí kíni gbogbo nkan wọ̀nyí lè jẹ́. Ó sì ṣe tí púpọ̀ wà nínú nwọn tí nwọ́n wípé Ámọ́nì ni Òrìṣà Nlá nnì, tí àwọn míràn wípé Òrìṣà Nlá ni ó rán an wa; Ṣùgbọ́n àwọn míràn bá gbogbo nwọn wí, tí nwọ́n wípé ohun abàmì ni, èyítí a rán wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Nífáì láti dãmú nwọn. Àwọn kan sì wà tí nwọ́n wípé Òrìṣà Nlá rán Ámọ́nì wá láti fi ìyà jẹ nwọ́n nítorí àìṣedẽdé nwọn; àti pé Òrìṣà Nlá nií ti máa nṣọ́ àwọn ará Nífáì, tĩ máa ngbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ nwọn; nwọn sì sọ pé Òrìṣà Nlá yìi ni ó ti papúpọ̀ nínú àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì run. Báyĩ sì ni ìjà bẹ̀rẹ̀sí pọ̀ lãrín nwọn. Bí nwọ́n sì ṣe njà yí, ọmọ-ọ̀dọ̀ obìnrin nã, èyítí ó ṣeé tí àwọn ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn nã fi kó jọ pọ̀ wa, nígbàtí ó sì rí ìjà èyítí ó wà lãrín àwọn ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn nã, inú rẹ̀ bàjẹ́ tó bẹ̃ tí ó fi sọkún. Ó sì ṣe tí ó lọ tí ó sì mú ayaba ní ọwọ́, pé bóyá òun lè gbée dìde sókè kúrò ní ilẹ̀; ní kété tí ó sì ti fọwọ́kàn ọwọ́ rẹ, ó dìde, ó sì wà lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ ó sì kígbe lóhùn rara, wípé; A! Jésù Olùbùkúnfún, ẹnití ó ti gbà mí kúrò nínú ọ̀run àpãdì búburú! A! Ọlọ́run Olùbùkúnfún, ẹ ṣãnú fún àwọn ènìyàn yí! Nígbàtí ó sì ti wí báyĩ, ó pàtẹ́wọ́ nítorítí ayọ̀ kún inú rẹ̀, ó sì sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí kò yé nwọn; nígbàtí ó sì ti ṣe eleyĩ tán, ó mú ọba, Lámónì lọ́wọ́, sì wọ́, ó dìde ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ ara rẹ̀. Bí òun, ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ṣe rí ìjà tí ó wà lãrín àwọn ènìyàn nã, ó jáde lọ ó sì bẹ̀rẹ̀sí bá nwọn wí, ó sì nkọ́ nwọn ní ẹ̀kọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí òun ti gbọ́ láti ẹnu Ámọ́nì; gbogbo àwọn tí nwọ́n sì gbọ́ ohùn rẹ ni nwọ́n gbàgbọ́, t í nwọ́n sì yí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa. Ṣùgbọ́n àwọn púpọ̀ wà lãrín nwọn tí nwọn kò fetísí ọ̀rọ̀ rẹ̀; nítorínã, nwọ́n bá ọ̀nà nwọn lọ. Ó sì ṣe nígbàtí Ámọ́nì dìde, ó sì jíṣẹ́ fún nwọn, àti sí gbogbo àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ Lámónì; gbogbo nwọn sì kéde fún àwọn ènìyàn nã ohun kan nã—pé ọkàn nwọn ti yí padà; pé nwọn kò ní ìfẹ́ àti ṣe búburu mọ́. Sì kíyèsĩ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó fi mọ̀ fún àwọn ènìyàn nã pé nwọ́n ti rí ángẹ́lì, tí nwọ́n sì ti bá nwọn sọ̀rọ̀; bákannã sì ni nwọ́n ṣe bá nwọn sọ àwọn ohun nípa Ọlọ́run, àti ti ìwà òdodo rẹ. Ó sì ṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gba ọ̀rọ̀ nwọn gbọ́; tí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ ni a sì ṣe ìrìbọmi fún; tí nwọ́n sì di olódodo ènìyàn, nwọ́n sì dá ìjọ-onígbàgbọ́ sílẹ̀ lãrín nwọn. Báyĩ sì ni iṣẹ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀ lãrín àwọn ará Lámánì; bẹ̃ sì ni Olúwa bẹ̀rẹ̀sí da Ẹ̀mí rẹ̀ lé nwọn; a sì ríi pé ó na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn ẹnití yíò bá ronúpìwàdà, tí nwọ́n sì gba orúkọ rẹ̀ gbọ́. 20 Olúwa rán Ámọ́nì lọ sí Mídónì láti tú àwọn arákùnrin rẹ̀ tí nwọ́n wà nínú túbú sílẹ̀—Ámọ́nì pẹ̀lú Lámónì pàdé bàbá Lámónì tí íṣe ọba lórí gbogbo ilẹ̀ nã—Ámọ́nì rọ ọba ogbó nnì kí ó fi àṣẹ sí ìtúsílẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 90 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí nwọ́n ti dá ìjọ-onígbàgbọ́ kan sílẹ̀ ní ilẹ̀ nã, tí ọba Lámónì fẹ́ kí Ámọ́nì bá òun lọ sí ilẹ̀ ti Nífáì, pé kí òun kí ó lè fi han bàbá òun. Ohùn Olúwa tọ Ámọ́nì wá, wípé: Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lọ sí ilẹ̀ ti Nífáì nã, nítorí kíyèsĩ, ọba nã yíò lépa èmí rẹ láti pa ọ́; ṣùgbọ́n ìwọ yio lọ sí ilẹ̀ Mídónì; nitori kíyèsĩ, arákùnrin rẹ, Áárọ́nì, pẹ̀lú Múlókì àti Ámmà wà nínú túbú. Nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Ámọ́nì ti gbọ́ èyí, ó wí fún Lámónì pé: Kíyèsĩ, àbúrò mi pẹ̀lú àwọnarákùnrin mi nwọ́n wà nínú túbú ní Mídónì, èmi yíò sì lọ kí èmi lè tú nwọn sílẹ̀. Nísisìyí, Lámónì wí fún Ámọ́nì pé: èmi mọ̀ pé nínú agbára Olúwa ìwọ lè ṣe ohun gbogbo. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi yíò bá ọ lọ sí ilẹ̀ Mídónì; nítorípé ọba ilẹ̀ Mídónì, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Ántíómnò, jẹ́ ọ̀rẹ́ fún mi; nítorínã èmi yíò lọ sí ilọ̀ Mídónì, kí èmi kí ó lè ṣe àpọ́nlé ọba ilẹ̀ nã, òun yíò sì yọ àwọn arákùnrin rẹ kúrò nínú túbú. Nísisìyí, Lámónì wí fún un pé: Tani ó wí fún ọ́ pé àwọn arákùnrin rẹ wà nínú túbú? Ámọ́nì wí fún un pé: Ẹnìkẹ́ni kò wí fún mi bíkòṣe Ọlọ́run; òun sì sọ fún mi—Lọ kí o sì tú àwọn arákùnrin rẹ sílẹ̀, nítorítí nwọ́n wà nínú túbú ní ilẹ̀ Mídónì. Nísisìyí nígbàtí Lámónì gbọ́ ohun y ĩ , ó pàṣẹ k í àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ pèsè àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀. Ó sì wí fún Ámọ́nì: Wá, èmi yíò bá ọ lọ sí ilẹ̀ Mídónì, níbẹ̀ ni èmi yíò rọ ọba nã pé kí ó yọ àwọn arákùnrin mi jáde nínú túbú. Ó sì ṣe bí Ámọ́nì àti Lámónì ṣe nrin ìrìnàjò nwọn lọ sí ibẹ̀, nwọ́n pàdé bàbá Lámónì, ẹnití íṣe ọba lórí gbogbo ilẹ̀ nã. Sì kíyèsĩ, bàbá Lámónì wí fún un pé: Kíni ìdí rẹ tí ìwọ kò fi wá sí ibi àpèjẹ ní ọjọ́ nlá nnì tí èmi se àpèjẹ fún àwọn ọmọ mi, àti fún àwọn àrá mi? Òun sì tún wí pé: Níbo ni ìwọ nlọ pẹ̀lú ará Nífáì yí, ẹnití ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ onírọ́ ènìyàn? Ó sì ṣe tí Lámónì sọ gbogbo ibi tí ó nlọ fún un, nítorítí ó bẹ̀rù láti ṣẹ̃. Ó sì tún sọ fún un gbogbo ìdí rẹ tí òun fi ndúró lẹ́hìn nínú orílẹ̀-èdè òun, tí òun kò fi lọ sí ibi àpèjẹ bàbá òun èyítí ó pèsè. Àti nísisìyí nigbati Lámónì ti ṣe àlàyé gbogbo nkan wọ̀nyí fún un kíyèsĩ, fún ìyàlẹ́nu rẹ̀, bàbá rẹ̀ bínú síi, ó sì wí pé: Lámónì, ìwọ fẹ́ tú àwọn ara Nífáì wọ̀nyí sílẹ̀, tí nwọn jẹ́ ìran òpùrọ́. Kíyèsĩ, ó ja àwọn bàbá wa lólè; àti nísisìyí àwọn ọmọ rẹ̀ tún wá sí ãrin wa, pé nípa ọgbọ́n àrékérekè nwọn, pẹ̀lú irọ́ nwọn, nwọn ó tàn wá kí nwọ́n tún lè jà wá lólè ohun ìní wa. Nísisìyí bàbá Lámónì pàṣẹ fún un pé kí ó pa Ámọ́nì pẹ̀lú idà. Òun sì tún pàṣẹ fún un pé kò gbọ́dọ̀ lọ sí ilẹ̀ Mídónì, ṣùgbọ́n kí ó padà pẹ̀lú òun lọ sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì. Ṣùgbọ́n Lámónì wí fún un pé: Èmi kò ní pa Ámọ́nì, bẹ̃ sì ni èmi kò ní padà lọ sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, ṣùgbọ́n èmi yíò lọ sí ilẹ̀ Mídónì, kí èmi lè tú àwọn arákùnrin Ámọ́nì sílẹ̀, nítorítí èmi mọ̀ pé ẹni tí ó tọ́ àti wòlĩ mímọ́ ti Ọlọ́run òtítọ́ ni nwọn íṣe. Nísisìyí, nígbàtí bàbá rẹ ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó bínú síi, ó sì fa idà rẹ yọ pé kí òun kí ó gẽ lulẹ̀. Ṣùgbọ́n Ámọ́nì jáde síwájú, ó sì wí fún un pé: Kíyèsĩ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ pa ọmọ rẹ; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó sàn kí ó kú ju kí ìwọ ó kú, nítorí kíyèsĩ, òun ti ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kú ní báyĩ, nínú ìbínú rẹ, ẹ̀mí rẹ kò lè rí ìgbàlà. Àti pẹ̀lú, ó jẹ́ ohun tí ó yẹ fún ọ láti máṣe èyí; nítorípé bí ìwọbá pa ọmọ rẹ, nítorípé aláìṣẹ̀ ènìyàn ni, ẹ̀jẹ̀ rẹ yíò ké láti ilẹ̀ wá sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fún ẹ̀san lórí rẹ; bóyá ìwọ yíò sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nu. Nísisìyí nígbàtí Ámọ́nì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún un, ó dáa lóhùn, ó wípé: Èmi mọ̀ pé tí èmi bá pa ọmọ mi, ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ ni èmi ta sílẹ̀; nítorípé ìwọ ni ó wá ọ̀nà láti paá run. Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti pa Ámọ́nì. Ṣùgbọ́n Ámọ́nì dojúkọ lílù rẹ, o si lu ọwọ rẹ kí ó má lè ríi lò. Nísisìyí, nígbàtí ọba nã ríi pé Ámọ́nì lè pa òun, ó bẹ̀rẹ̀sí ṣípẹ̀ pẹ̀lú Ámọ́nì pé kí ó dá ẹ̀mí òun sí. Ṣùgbọ́n Ámọ́nì gbé idà rẹ̀ sókè, ó sì wí fún un pé: Kíyèsĩ, èmi yíò pa ọ́, àfi tí ìwọ bá gbà kí a kó arákùnrin mi jáde kúrò nínú túbú. Nísisìyí nítorítí ọba bẹ̀rù kí ó má sọ ẹ̀mí ara òun nù, ó wípé: Bí ìwọ bá dá mi sí, èmi yíò fún ọ ní ohunkóhun tí ìwọ lè bẽrè, àní títí fi dé ìlàjì ìjọba yí. Nísisìyí nígbàtí Ámọ́nì ríi pé òun ti mú ọba nã ṣe bí òun ti fẹ́, ó wí fún un pé: Bí ìwọ bá gbà kí a kó àwọn arákùnrin mi jáde kúrò nínú túbú, àti kí Lámónì sì tún fi ọwọ́ mú ìjọba rẹ, kí ìwọ má sì bínú síi, ṣùgbọ́n kí ìwọ gbà kí ó ṣe ìfẹ́ rẹ nínú ohunkóhun tí ó lè gbèrò, nígbàyí ni èmi yíò dá ọ sí; bíkòjẹ́bẹ̃ èmi yíò gé ọ lulẹ̀. Nísisìyí nígbàtí Ámọ́nì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ọba nã bẹ̀rẹ̀sí yọ̀ nítorí ẹ̀mí rẹ̀. Nígbàtí ó ríi pé Ámọ́nì kò ní ìfẹ́ láti pa òun run, nígbàtí ó sì tún rí ìfẹ́ nlá èyítí ó ní fún ọmọ òun Lámónì, ẹnu yã púpọ̀púpọ̀, ó sì wípé: Nítorípé èyí nìkan ni ìwọ bẽrè, pé kí èmi tú àwọn arákùnrin rẹ sílẹ̀, àti kí èmi gbà kí Lámónì ọmọ mi sì fi ọwọ́ mú ìjọba tirẹ̀, kíyèsĩ èmi yio gbà fún ọ kí ọmọ mi kí ó fọwọ́ mú ìjọba tirẹ̀ láti ìgbà yí lọ àti títí láéláé; èmi kò sì ní jọba lórí rẹ mọ́. Èmi yíò sì tún gbà fún ọ kí a tú àwọn arákùnrin rẹ sílẹ̀ nínú túbú, kí ìwọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ nã sì wá sí ọ̀dọ̀ mi nínú ìjọba mi; nítorípé èmi yíò ṣe àfẹ́rí rẹ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nítorípé ẹnu ya ọba nã púpọ̀ fún ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ, àti fún ọ̀rọ̀ tí ọmọ rẹ̀ Lámónì ti sọ, nítorínã ó ní ìfẹ́ lati kọ́ nípa awọn ọ̀rọ̀ náà. Ó sì ṣe tí Ámọ́nì àti Lámónì mú ọ̀nà pọ̀n lọ sí ìrìnàjò nwọn sí ilẹ̀ Mídónì. Lámónì sì rí ojú rere ọba ilẹ̀ nã; nítorínã nwọn mú àwọn arákùnrin Ámọ́nì jáde kúrò nínú túbú. Nígbàtí Ámọ́nì sì bá nwọn pàdé, ó kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí kíyèsĩ, ihoho ni nwọ́n wà, awọ ara nwọn sì ti bó kúrò púpọ̀púpọ̀ nítorítí a dè nwọ́n pẹ̀lú okùn líle. Pẹ̀lú pé ebi, òùngbẹ, àti onírurú ìpọ́njú ti jẹ nwọ́n níyà; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n ní sũrù nínú gbogbo ìjìyà nwọn wọ̀nyí. Bí o sì ti ríi báyĩ, ó jẹ́ ìpín nwọn láti bọ́ sí ọ́wọ́ àwọn ènìyàn líle pẹ̀lú ọlọ́kàn líle; nítorínã nwọn kò gbọ tiwọn, nwọ́n sì jù nwọ́n síta, nwọ́n sì nà nwọ́n, nwọ́n sì ti lé nwọn láti ilé kan dé òmíràn, àti lai ibìkan dé òmíràn, àní títí nwọn fi dé ilẹ̀ Mídónì; níbẹ̀ sì ni nwọ́n ti mú nwọn tí nwọn sì jù nwọ́n sínú túbú, tí nwọ́n sì dè wọ́n pẹ̀lúokùn líle, tí nwọ́n sì fi nwọ́n sínú túbú fún ọjọ́ pípẹ́, tí Lámónì àti Ámọ́nì sì tú nwọn sílẹ̀. Akọsílẹ̀ nípa ìwãsù Áárọ́nì, àti Múlókì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn, sí àwọn ará Lámánì. Èyítí a kọ sí àwọn orí 21 títí ó fi dé 26 ní àkópọ̀. 21 Áárọ́nì nkọ́ àwọn ará Ámálẹ́kì ní ẹ̀kọ́ nípa Krístì àti ètùtù rẹ̀—Nwọ́n gbé Áárọ́nì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ jù sínú túbú ní Mídónì—Lẹ́hìn ìtúsílẹ̀ nwọn, nwọ́n nkọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù, nwọ́n sì yí ọ̀pọ̀ lọ́kàn padà—Lámónì fún àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì ní òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn tí ó bá wù wọ́n. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí nígbàtí Ámọ́nì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ ya ara nwọn sílẹ̀ ní etí-ìlú ti ilẹ̀ àwọn ará Lámánì, kíyèsĩ, Áárọ́nì mú ọ̀nà ìrìn-àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìhà ilẹ̀ èyítí àwọn ará Lámánì npè ní Jerúsálẹ́mù, tí nwọ́n sọ lórúkọ ilẹ̀ ìbí àwọn bàbá nwọn; ó sì jìnà síwájú, tí ó wa lẹ́bá etí-ìlú Mọ́mọ́nì. Nísisìyí, àwọn ará Lámánì pẹ̀lú àwọn ará Ámálẹ́kì, àti àwọn ènìyàn Ámúlónì ti kọ́ ilu nlá kan, èyítí nwọn pe orúkọ rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Nísisìyí, àwọn ará Lámánì jẹ́ ọlọ́kàn líle ènìyàn, ṣùgbọ́n, àwọn ará Ámálẹ́kì àti àwọn ará Ámúlónì síbẹ̀síbẹ̀ le lọ́kàn jù nwọ́n lọ; nítorínã, nwọ́n jẹ́ kí ọkàn àwọn ará Lámánì túbọ̀ le síi, pé kí nwọ́n lágbára síi nínú ìwà búburú àti ìwà ìríra nwọn gbogbo. Ó sì ṣe tí Áárọ́nì wá sí ìlú-nlá Jerúsálẹ́mù, tí ó sì kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí àwọn ará Ámálẹ́kì. Ó sì bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí nwọn nínú àwọn sínágọ́gù nwọn, nítorítí nwọ́n ti kọ́ àwọn sínágọ́gù bí àwọn tí ipa Néhórì; nítorípé púpọ̀ nínú àwọn ará Ámálẹ́kì pẹ̀lú àwọn ará Ámúlónì jẹ́ ti ipa ti Néhórì. Nítorínã, bí Áárọ́nì ti wọ inú ọ̀kan àwọn sínágọ́gù nwọn láti wãsù sí àwọn ènìyàn nã, bí ó sì ṣe nbá nwọn sọ̀rọ̀ lọ, kíyèsĩ, ará Ámálẹ́kì kan dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀sí ta kọ́, wípé: Kíni èyí nnì tí ìwọ jẹ́rĩ sí? Ìwọ ha ti rí ángẹ́lì bí? Kíni àwọn ángẹ́lì kò ṣe farahàn sí wá? Kíyèsĩ, ṣe àwọn ènìyàn yí kò dára tó àwọn ènìyàn rẹ ni? Ìwọ wípé, afi bí àwa bá ronúpìwàdà, àwa yio ṣègbé. Báwo ni ìwọ ṣe mọ́ èrò àti ìfẹ́ inú ọkàn wa? Báwo ni ìwọ ṣe mọ̀ pé ó yẹ fún wa láti ronúpìwàdà? Báwo ni ìwọ ṣe mọ̀ wípé àwa kĩ ṣe ènìyàn rere? Kíyèsĩ, àwa ti kọ́ àwọn ibi-mímọ́, àwa sì máa nkó ara wa jọ láti sin Ọlọ́run. Àwa gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run yíò gba ènìyàn gbogbo là. Nísisìyí Áárọ́nì sọ fún un pé: Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ wípé Ọmọ Ọlọ́run yíò wá láti ra aráyé padà kurò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn? Ọkùnrin nã sì wí fún un pé: Àwa kò gbàgbọ́ pé ìwọ mọ́ èyí tí ó jẹ́ bẹ̃. Àwa kò gbàgbọ́ nínú àwọn àṣà aṣiwèrè wọ̀nyí. Àwa kò gbàgbọ́ pé ìwọ mọ́ àwọn ohun èyítí nbọ̀wá bẹ̃ni àwa kòsì gbàgbọ́ pé àwọn bàbá rẹ àti àwọn bàbá wa mọ̀ nípa àwọn ohun tí nwọ́n sọ, nípa èyítí nbọ̀wá. Nísisìyí Áárọ́nì bẹ̀rẹ̀sí ṣí àwọn ìwé-mímọ́ fún nwọn nípa bíbọ̀ Krístì, àti nípa àjĩnde òkú, àti pẹ̀lú pé kò lè sí ìràpadà fún aráyé, bíkòṣe nípa ikú àti ìjìyà Krístì, àti ètùtù ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ó sì ṣe, bí òun ṣe nla àwọn nkan wọ̀nyí yé nwọn, nwọ́n bínú síi, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí fĩ ṣe ẹlẹ́yà; nwọn kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó nsọ mọ. Nítorínã, nígbàtí ó ríi pé nwọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ òun mọ, ó jáde kúrò nínú sínágọ́gù nwọn, ó sì wá sí inú ìletò kan tí à npe orúkọ rẹ̀ ní Anai-Ántàì, níbẹ̀ ní ó sì rí Múlókì tí ó nwãsù ọ̀rọ̀-nã sí nwọn; pẹ̀lú Ámmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀. Nwọn sì njiyàn pẹ̀lú púpọ̀ nwọn nípa àwọn ọ̀rọ̀-nã. Ó sì ṣe, tí nwọ́n ríi pé àwọn ènìyàn nã sé ọkàn nwọn le síbẹ̀, nítorínã nwọ́n jáde kúrò níbẹ̀ nwọ́n sì wá sí ilẹ̀ Mídónì. Nwọ́n sì wãsù ọ̀rọ̀-nã sí púpọ̀ àwọn ènìyàn nã, díẹ̀ sì gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí nwọ́n kọ́ nwọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃ nwọ́n mú Áárọ́nì àti àwọn kan nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ nwọ́n sì jù nwọn sínú túbú, àwọn tí o kú sì sa jáde kúrò nínú ilẹ̀ Mídónì lọ sí àwọn agbègbè tí ó wà ní àyíká. Àwọn ti nwọ́n jù sínú túbú jẹ ìyà púpọ̀, a sì tú nwọn sílẹ̀ nípasẹ̀ Lámónì àti Ámọ́nì, a sì fún nwọn ní oúnjẹ, a sì wọ aṣọ fún nwọn. Nwọ́n sì tún jáde lọ láti lọ wãsù ọ̀rọ̀-nã, báyĩ sì ni a ṣe tú nwọn sílẹ̀ nínú túbú nígbà àkọ́kọ́; báyĩ sí ni ìyà ṣe jẹ nwọ́n. Nwọ́n sì jáde lọ, sí ibikíbi tí Ẹ̀mí-Olúwa darí nwọn sí, tí nwọ́n nwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú gbogbo sínágọ́gù àwọn ará Ámálẹ́kì, tàbí ní ibi àpéjọ àwọn ará Lámánì tí nwọ́n bá gbà nwọ́n wọlé. Ó sì ṣe tí Olúwa sí bẹ̀rẹ̀sí bùkún nwọn, tó bẹ̃ tí nwọ́n mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí ìmọ̀ òtítọ́; bẹ̃ni, nwọ́n yí púpọ̀ lọ́kàn padà nípa ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, àti nípa àṣà àwọn bàbá nwọn, tí kò tọ̀nà. Ó sì ṣe tí Ámọ́nì àti Lámónì padà kúrò ní ilẹ̀ Mídónì, lọ sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, èyítí íṣe ilẹ̀ íní nwọn. Ọba Lámónì kò sì gbà kí Ámọ́nì sin òun, tàbí kí ó jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ òun. Ṣùgbọ́n ó pàṣẹ kí nwọ́n kọ́ àwọn sínágọ́gù ní ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì; ó sì paṣẹ pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀, tàbí àwọn ènìyàn tí nwọ́n wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀, kí nwọ́n kó ara nwọn jọ papọ̀. Ó sì yọ nítorí nwọn, ó sì kọ́ nwọn ní ohun púpọ̀. Òun sì tún la ohun púpọ̀ yé nwọn pé ènìyàn tí ó wà lábẹ́ ìjọba òun ni nwọ́n íṣe, àti pé òmìnira-ènìyàn ni nwọ́n íṣe, pé a ti sọ nwọ́n di òmìnira kúrò nínú ìmúnisin ọba, tĩ ṣe bàbá òun; nítorípé bàbá òun ti fún òun ní àṣẹ láti jọba lórí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, àti gbogbo ilẹ̀ tí ó yíi ká. Ó sì tún fi yé nwọn pé nwọ́n ní ànfàní fún sísin Olúwa Ọlọ́run nwọn gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú nwọn, ní ibikíbi tí nwọ́n bá wà, tí ó bá ti jẹ́ orí ilẹ̀ èyítí ó wà lábẹ́ ìjọba ọba Lámónì. Ámọ́nì sì wãsù sí àwọn ènìyàn ọba Lámónì; ó sì ṣe tí ó kọ́ nwọn ní ẹ̀kọ́ nípa ohun gbogbo nípa òdodo. Ó sì ngbà nwọ́n níyànjú lójojúmọ́, láìsinmi; nwọ́n sì fi etí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, nwọ́n sì fi ìtara pa òfin Ọlọ́run mọ́. 22 Áárọ́nì kọ́ bàbá Lámónì nípa dídá ayé; ìṣubú Ádámù, àti ìlànà ìràpadà nípasẹ̀ Krístì—Ọba nã àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ ni a yí l’ọ́kàn padà—A ṣe àlàyé lórí bí a ṣe pín ilẹ̀ nã lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí, bí Ámọ́nì ṣe tẹ̀síwájú nípa kíkọ́ àwọn ará Lámónì, a ó padà sí àkọsílẹ̀ Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀; nítorípé lẹ́hìn tí ó fi ilẹ̀ Mídónì sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ darí rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Nífáì, àní lọ sí ilé ọba tí ó wà lórí gbogbo ilẹ̀ nã, àfi ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì; òun sì ni bàbá Lámónì. Ó sì ṣe tí ó tọ̣́ lọ, sínú ãfin ọba, pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀; ó sì tũbá níwájú ọba, ó sì wí fún un pé: Kíyèsĩ, A! ọba, arákùnrin Ámọ́nì ni àwa í ṣe, ẹnití ìwọ ti tú sílẹ̀ nínú tũbú. Àti nísisìyí, A! ọba, tí ìwọ yíò bá dá ẹ̀mí wa sí àwa yíò ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ. Ọba sì wí fún nwọn pé: Ẹ dìde, nítorítí èmi yíò dá ẹ̀mí nyin sí, èmi kò sì ní gbà kí ẹ jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ fún mi; ṣùgbọ́n èmi yíò fi dandan lée pé kí ẹ̀yin dúró níwájú mi; nítorítí ọkàn mi kò balẹ̀ nípa inú-rere àti títóbi ọ̀rọ̀ Ámọ́nì arákùnrin nyín; èmi sì fẹ́ mọ́ ìdí tí kò fi jáde wá láti Mídónì pẹ̀lú nyín. Áárọ́nì sì wí fún ọba nã pé: Kíyèsĩ, Ẹ̀mí Olúwa ti darí rẹ̀ sí ibòmíràn; ó ti lọ sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, láti kọ́ àwọn ará Lámónì ní ẹ̀kọ́. Nísisìyí, ọba nã wí fún nwọn pé: Kíni èyí yĩ tí ìwọ ti wí nípa Ẹ̀mí Olúwa? Kíyèsĩ, èyí yĩ ni ohun tí ó nrú mi lójú. Àti pẹ̀lú, kíni èyí yĩ tí Ámọ́nì wí—Bí ìwọ yíò bá ronúpìwàdà a ó gbà ọ́ là, àti pé bí ìwọ kì yíò bá ronúpìwàdà, a ó ta ọ́ nù ní ọjọ́ ìkẹhìn? Áárọ́nì sì dá a lóhùn ó sì wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan nbẹ? Ọba nã sì wípé: Èmi mọ̀ pé àwọn ará Ámálẹ́kì sọ wípé Ọlọ́run kan nbẹ, èmi sì ti gbà nwọ́n lãyè kí nwọ́n kọ́ àwọn ibi-mímọ́, kí nwọ́n lè péjọ láti lè sìn ín. Nísisìyí, bí ìwọ bá sì sọ wípé Ọlọ́run kan nbẹ, kíyèsĩ èmi yíò gbàgbọ́. Àti nísisìyí nígbàtí Áárọ́nì gbọ́ èyí, ọkàn rẹ bẹ̀rẹ̀sí yọ̀, ó sì wípé: Kíyèsĩ, dájúdájú bí ìwọ ti wà lãyè, Á! ọba, Ọlọ́run kan nbẹ. Ọba nã sì wí pé: Njẹ́ Ọlọ́run ha ni Òrìṣà Nlá nnì ẹnití ó mú àwọn bàbá wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù? Áárọ́nì sì wí fún un pé: Bẹ̃ni òun ni Òrìṣà Nlá nã, òun ni ó sì dá ohun gbogbo ní ọ̀run àti ní ayé. Njẹ́ ìwọ gba èyí gbọ́ bí? Òun sì wípé: Bẹ̃ni, èmi gbàgbọ́ wípé Òrìṣà Nlá nã ni ó dá ohun gbogbo, èmi sì fẹ́ kí ìwọ kí ó sọ nípa àwọn ohun wọ̀nyí fún mi, èmi yíò sì gba àwọn ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́. Ó sì ṣe tí Áárọ́nì rí i pé ọba ṣetán láti gba àwọn ọ̀rọ̀ òun gbọ́, ó bẹ̀rẹ̀ láti dídá Ádámù, ó sì ka àwọn ìwé-mímọ́ sí Ọba—bí Ọlọ́run ṣe dá ènìyàn ní àwòránara rẹ̀, tí Ọlọ́run sì fún un ní àwọn òfin, àti pé nítorí ìwàìrékọjá, ènìyàn ti ṣubú. Áárọ́nì sì la àwọn ìwé-mímọ́ yé e ní kíkún láti ìgbà dídá Ádámù, ó sì fi ìṣubú ènìyàn yé e pẹ̀lú ipò àìmọ́ inú èyí tí nwọ́n wà, àti pẹ̀lú ìlànà ìràpadà, èyítí a ti pèsè sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nípasẹ̀ Krístì, fún gbogbo ẹnìkẹ́ni tí yíò bá gba orúkọ rẹ̀ gbọ́. Níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn sì ti ṣubú, òun tìkalára rẹ̀ kò lè rí ojú rere àti ìyọ́nú; ṣùgbọ́n ìjìyà àti ikú Krístì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nípa ìgbàgbọ́ àti ìrònúpìwàdà, àti bẹ̃bẹ̃ lọ; àti pé òun ni ó já ìdè ikú, tí isà-òkú kò lè ní ìṣẹ́gun, tí oró ikú yíò di gbígbémì nínú ìrètí ògo; Áárọ́nì sì la gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí yé ọba ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí Áárọ́nì ti la àwọn ohun wọ̀nyí yée, ọba nã wípé: Kíni èmi yíò ṣe tí èmi yíò fi rí ìyè àìnípẹ̀kun èyítí ìwọ ti sọ nípa rẹ̀? Bẹ̃ni, kíni èmi yíò ṣe tí a ó fi bí mi nipa ti Ọlọ́run, tí a ó fi fa ẹ̀mí búburú yìi tú jáde kúrò ní àyà mi, tí èmi yíò sì gba ẹ̀mí rẹ̀, kí èmi lè kún fún ayọ̀, tí èmi kò sì ní di títa dànù ní ọjọ́ ìkẹhìn? Kíyèsĩ, èyí ni ó wí, èmi yíò fi ohun gbogbo tí mo ní sílẹ̀, bẹ̃ni, èmi yíò kọ ìjọba mi sílẹ̀, kí èmi lè gba ayọ̀ nlá yĩ. Ṣùgbọ́n Áárọ́nì wí fún un pé: Bí ìwọ bá ní ìfẹ́ sí ohun wọ̀nyí, bí ìwọ bá lè rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, bẹ̃ni, bí ìwọ bá lè ronúpìwàdà gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, tí ìwọ sì wólẹ̀ níwájú Ọlọ́run, tí ìwọ sì képe orúkọ rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, tí ìwọ sì gbàgbọ́ pé ìwọ yíò rí gbà, nígbànã ni ìwọ yíò rí ìrètí tí ìwọ nṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọkàn rẹ gbà. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí Áárọ́nì ti parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ọba nã wólẹ̀ níwájú Ọlọ́run lórí ekún rẹ; bẹ̃ni, àní ó na ara rẹ̀ gbalaja lórí ilẹ̀, ó sì kígbe l’óhùn rara, pé: A! Ọlọ́run, Áárọ́nì ti wí fún mi pé Ọlọ́run kan nbẹ; bí Ọlọ́run bá sì nbẹ, tí ìwọ bá sì í ṣe Ọlọ́run, njẹ́ kí ìwọ kí ó fi ara rẹ hàn mí, èmi yíò sì kọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sílẹ̀ kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́ àti kí èmi lè jínde kúrò nínú ipò-òkú, àti kí a lè gbà mí là ní ọjọ́ ìkẹhìn. Àti nísisìyí, nígbàtí ọba nã ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, agbára Ọlọ́run kọ lù ú ó sì dà bí èyítí ó ti kú. Ó sì ṣe tí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sáré lọ wí fún ayaba ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọba. Ó sì tọ ọba wá; nígbàtí ó sì ríi tí ó dùbúlẹ̀ bí èyítí ó ti kú, àti pẹ̀lú, Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ bí ẹni wípé àwọn ni nwọn ṣeé tí ó fi ṣubú, ó bínú sí nwọn, ó sì pàṣẹ pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tàbí àwọn ìránṣẹ́ ọba, mú nwọn, kí nwọ sì pa nwọ́n. Nísisìyí, àwọn ìránṣẹ́ yĩ ti rí ohun tí ó fã tí ọba fi ṣubú lulẹ̀, nítorínã nwọn kò lè fi ọwọ́ kan Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀; nwọ́n sì ṣìpẹ̀ fún ayaba wípé: Kíni ìwọ ha ṣe pàṣẹ fún wa pé kí àwa kí ó pa àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, nígbàtí kíyèsĩ, ọ̀kan nínú nwọn lágbára jù wá lọ? Nítorínã àwa yíò ṣègbé níwájú nwọn. Nísisìyí nígbàtí ayaba rí ìbẹ̀rù àwọn ìránṣẹ́ nã, òun pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù púpọ̀, nítorí kí ohun búburú kan máṣe ṣẹlẹ̀ síi. Ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kínwọ́n lọ pe àwọn ènìyàn gbogbo wá, kí nwọ́n lè pa Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀. Nísisìyí nígbàtí Áárọ́nì rí ìpinnu ayaba nã, tí òun pẹ̀lú sì mọ́ líle ọkàn àwọn ènìyàn nã, ẹ̀rù bã kí àwọn ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn má ṣe kó ara nwọn jọ, kí àríyànjiyàn àti ìrúkèrúdò sì bẹ́ sílẹ̀ lãrín nwọn; nítorínã, ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì gbé ọba nã dìde kúrò nílẹ̀, ó sì wí fún un pé: Dìde dúró. Òun sì dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì gba okun sára. Nísisìyí a ṣe èyí níwájú ayaba àti púpọ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́. Nígbàtí nwọ́n sì ríi, ẹnu yà nwọ́n púpọ̀, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀rù. Ọba nã sì dìde dúró, ó sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fun wọn tó bẹ̃ tí ayí gbogbo agbo ilé rẹ̀ padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa. Nísisìyí ọ̀gọ̣́rọ̀ àwọn ènìyàn péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ayaba ti pàṣẹ, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìkùnsínú lãrín ara nwọn nítorí Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọba dìde dúró lãrín nwọn ó sì njíṣẹ́ fún nwọn. A sì tù nwọn l’ọ́kàn sí Áárọ́nì pẹ̀lú àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Ó sì ṣe nígbàtí ọba rí i pé a ti tù nwọ́n l’ọ́kàn, ó pàṣẹ pé kí Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde wá sí ãrín àwọn ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn nã, kí nwọ́n sì wãsù ọ̀rọ̀ nã sí nwọn. Ó sì ṣe tí ọba ṣe ìkéde ní gbogbo ilẹ̀ nã, lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀ tí nwọ́n wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè, tí ó wà ní àyíká títí fi dé etí òkun, ní ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, àwọn èyítí ó pa ãlà pẹ̀lú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà pẹ̀lú aginjù tẹ̃rẹ́ èyítí ó nà láti òkun tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn àní sí èyí tí ó wà ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti yíká gbogbo ìhà etí òkun, àti ìhà aginjù tí ó wà ní apá àríwá ní ẹ̀bá ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, títí dé etí ilẹ̀ Mántì, nítòsí orísun odò Sídónì, èyítí ó ṣàn láti apá ìlà-oòrùn lọ sí apá ìwọ̀-oòrùn—báyĩ sì ni a ṣe pa ãlà àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Nífáì. Nísisìyí, àwọn ará Lámánì tí nwọ́n jẹ́ ọ̀lẹ ènìyàn nínú nwọn ngbé inú aginjù, nwọn a sì máa gbé nínú àgọ́; nwọ́n sì tàn ká kiri inú aginjù ní apá ìwọ̀-oòrùn, ní ilẹ̀ Nífáì; bẹ̃ni, àti ní apá ìwọ̀oòrùn ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nítósí etí òkun, àti ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ilẹ̀ Nífáì, ní ibi ìní àkọ́kọ́ àwọn bàbá nwọn, tí nwọ́n sì fi ara pẹ́ etí-òkun. Àti pẹ̀lú pé àwọn ará Lámánì púpọ̀ ni ó wà ní apá ìhà ìlà-oòrùn nítòsí etí òkun, níbití àwọn ará Nífáì ti lé nwọn sí. Báyĩ sì ni ó rí tí àwọn ará Lámánì fẹ́rẹ̀ yí àwọn ará Nífáì ká; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ará Nífáì ti gba gbogbo apá gũsù ilẹ̀ tí ó kángun sí aginjù, ní ibi orísun odò Sídónì, láti apá ìlà-oòrùn títí dé apá ìwọ̀-oòrùn, yíká kiri apá ibi aginjù; ní apá àríwá, àní títí fi dé ilẹ̀ nã èyítí nwọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ibi-Ọ̀pọ̀. Ó sì pa ãlà pẹ̀lú ilẹ̀ tí a npè ọrúkọ rẹ̀ ní Ibi-Ahoro, nítorítí ó jìnà réré sí apá àríwá, tí ó fi dé ibi ilẹ̀ èyítí àwọn ènìyàn ngbé tẹ́lẹ̀rí ṣùgbọ́n tí nwọ́n ti parun, ní ti egungun àwọn tí a ti sọ nípa nwọn ṣãjú, ilẹ̀ èyítí ó jẹ́ pé àwọn ará Sarahẹ́múlà ni ó wá a rí, nítorípé òun ní ibi tí nwọ́n ti kọ́kọ́ gúnlẹ̀. Nwọ́n sì ti ibẹ̀ wá lọ sí apá gũsù aginjù nã. Báyĩ ní ó rí tí a fi npe ilẹ̀ apá àríwá ní Ibi-Ahoro, àti ilẹ̀ ti o wà ní apá gũsù ni a pè ní Ibi-Ọ̀pọ̀, nítorípé aginjù nã kún fún onírurú ẹranko ìgbẹ́ ní oríṣiríṣi, nínú àwọn èyítí ó ti wá láti ilẹ̀ àríwá fún oúnjẹ. Àti nísisìyí, ìrìnàjò ọjọ́ kan àti ãbọ̀ ni ó jẹ́ fún ará Nífáì láti ãlà lãrín Ibi-Ọ̀pọ̀ àti Ibi-Ahoro, láti òkun tí ó wà ní apá ìlà-oòrùn títí dé òkun èyítí ó wà ní apá ìwọ̀-oòrùn; báyĩ sì ni ó rí, tí omi fẹ́rẹ̀ yí ilẹ̀ Nífáì pẹ̀lú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà ká, tí ilẹ̀ tẹ́rẹ́ kan sì wà lãrín ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà àríwá àti èyítí ó wà ní gũsù. Ó sì ṣe tí àwọn ará Nífáì ti tẹ Ibi-Ọ̀pọ̀ dó, àní láti apá ìhà ìlà oòrùn títí fi dé òkun èyítí ó wà ní ìwọ oòrùn, báyĩ sì ni ó rí tí àwọn ara Nífáì, nínú ọgbọ́n nwọn, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ àti ọmọ ogun nwọn, ti há àwọn ará Lámánì mọ́ ní apá gũsù, kí nwọn má bã lè ní ìní kankan mọ́ ní apá àríwá, kí nwọn má bã lè wọ inú ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà apá àríwá. Nítorínã, àwọn ará Lámánì kò ní ìní kankan mọ́, àfi ní ilẹ̀ Nífáì pẹ̀lú aginjù tí ó yíi ka. Nísisìyí eleyĩ jẹ́ ohun ọgbọ́n fún àwọn ará Nífáì—nítorípé àwọn ará Lámánì jẹ́ ọ̀tá fún nwọn, nwọ́n kọ̀ láti gba ìyà àwọn ará Lámánì ní gbogbo ibi, àti pé kí nwọn le ni orílẹ̀-èdè èyítí nwọ́n lè sálọ sí, bí nwọ́n bá ti fẹ́. Àti nísisìyí èmi, lẹ́hìn tí mo ti sọ eleyĩ, padà sórí ọ̀rọ̀ nípa àkọsílẹ̀ Ámọ́nì àti Áárọ́nì, Òmnérì àti Hímnì, àti àwọn arákùnrin nwọn. 23 A ṣe ìkéde òmìnira ẹ̀sìn—Àwọn ará Lámánì tí ó wà ní ilẹ̀ àti ìlú-nlá méje ni a yí lọ́kàn padà—Nwọ́n pe ara nwọn ní Kòṣe-Nífáì-Léhì, a sì dá nwọn nídè kúrò nínú ègún nã—Àwọn ará Ámálẹ́kì àti àwọn ará Ámúlónì kọ òtítọ́ nã sílẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa. Kíyèsĩ, báyĩ ni ó sì ṣe tí ọba àwọn ará Lámánì ṣe ìkéde lãrín gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀, pé kí nwọn máṣe fi ọwọ́ kan Ámọ́nì, tàbí Áárọ́nì, tàbí Òmnérì, tàbí Hímnì, tàbí èyíkéyĩ nínú àwọn arákùnrin nwọn tí yíò bá lọ wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ní ibikíbi tí wọ́n lè wà lórí ilẹ̀ nwọn. Bẹ̃ni, ó sì fi àṣẹ ránṣẹ́ lãrín nwọn pé nwọn kò gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ kan nwọ́n láti dè nwọ́n, tàbí láti gbé nwọn sínú tũbú; bẹ̃ni nwọn kò gbọ́dọ̀ tu itọ́ sí nwọn lára, tàbí lù nwọ́n, tàbí lé nwọn jáde kúrò nínú sínágọ́gù nwọn, tàbí kí nwọ́n nà nwọ́n ní pàṣán; nwọn kò gbọ́dọ̀ sọ nwọ́n ní òkúta, ṣùgbọ́n pé kí nwọ́n máa wọ ilé nwọn láìní ìdíwọ́, àti tẹ́mpìlì nwọn pẹ̀lú, àti àwọn ibi-mímọ́ nwọn. Báyĩ nwọn yíò sì lè lọ wãsù ọ̀rọ̀ nã gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú nwọn, nítorítí a ti yí ọkàn ọba padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa, àti gbogbo agbo ilé rẹ̀; nítorínã, ó fi ìkéde rẹ̀ nã ránṣẹ́ jákè-jádò ilẹ̀ nã sí àwọn ènìyàn rẹ̀, pé kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máṣe ní ìdènà, ṣùgbọ́n pé kí ó lọ jákèjádò ilẹ̀ nã, kí àwọn ènìyàn rẹ̀ lè gba ìdánilójú nípa àṣà búburú àwọn bàbá nwọn, àti pé kínwọ́n lè mọ̀ dájú pé arákùnrin ni gbogbo nwọn jẹ́ fún ara nwọn, àti pé nwọn kò gbọ́dọ̀ pànìyàn, tàbí ṣe ìkógun, tàbí jalè, tàbí ṣe àgbèrè, tàbí hùwà búburú kankan. Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí ọba ti fi ìkéde nã ránṣẹ́, ni Áárọ́nì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ láti ìlú dé ìlú, àti láti ilé ìjọsìn kan dé òmíràn, tí nwọ́n sì ndá ìjọ̀-onígbàgbọ́ sílẹ̀, tí nwọ́n sì nyan àwọn àlùfã àti olùkọ́ni sọ́tọ̀ jákè-jádò ilẹ̀ nã lãrín àwọn ará Lámánì, láti wãsù àti láti kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lãrín nwọn; báyĩ ni nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe àṣeyọrí púpọ̀púpọ̀. A sì mú ẹgbẹ̃gbẹ̀rún wá sí ìmọ̀ Olúwa, bẹ̃ni, ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ni a mú láti gbàgbọ́ nínú àṣà àwọn ará Nífáì; a sì kọ́ nwọn ní àkọsílẹ̀ àti ìsọtẹ́lẹ̀ èyítí à ngbé lé nwọn lọ́wọ́, àní títí di òní. Bí Olúwa sì ti wà lãyè, bẹ̃ni ó sì dájú, tí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, tàbí tí gbogbo àwọn tí a mú wá sí ìmọ̀ òdodo nípa ìwãsù Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, nípasẹ̀ ẹ̀mí ìfihàn àti ti ìsọtẹ́lẹ̀, àti agbára Ọlọ́run tí ó nṣe iṣẹ́ ìyanu nínú nwọn—bẹ̃ni, mo wí fún nyin, bí Olúwa ti wà lãyè, gbogbo àwọn ará Lámánì tí nwọ́n gbàgbọ́ nínú ìwãsù nwọn, tí nwọ́n sì yípadà sí ọ̀dọ̀ Olúwa, kò ṣubú kúrò lọ́nà nã mọ́. Nítorítí nwọ́n di ènìyàn olódodo; nwọ́n sì kó ohun ìjà ọ̀tẹ̀ nwọn lélẹ̀, tí nwọn kò bá Ọlọ́run jà mọ́, tàbí ẹnìkẹ́ni nínú arákùnrin nwọn. Nísisìyí, àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí a yí lọ́kàn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa: Àwọn ènìyàn Lámánì tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì; Àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn Lámánì tí nwọ́n wà ní ilẹ̀Mídónì; Àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn Lámánì tí nwọ́n wà ní ìlú-nlá ti Nífáì; Àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn Lámánì tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Ṣílómù, àti tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Ṣẹ́múlónì, àti nínú ìlú-nlá Lémúẹ́lì, àti nínú ìlú-nlá Ṣímnílọ́mù. Àwọn wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ìlú-nlá àwọn ará Lámánì tí a yí lọ́kàn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa; àwọn sì ni nwọ́n kó àwọn ohun ìjà ọ̀tẹ̀ nwọn sílẹ̀, bẹ̃ni, gbogbo ohun ìjà ogun nwọn; ará Lámánì sì ni gbogbo nwọn í ṣe. Àwọn ará Ámálẹ́kì kò sì yípadà, àfi ẹnìkan ṣoṣo; bẹ̃ni kò sì sí nínú àwọn ará Ámúlónì; ṣùgbọ́n nwọ́n sé àyà nwọn le, àti àyà àwọn ará Lámánì ní apá ìhà ilẹ̀ nã níbikíbi tí nwọ́n gbé, bẹ̃ni, àti gbogbo ìletò nwọn, àti gbogbo ìlú-nlá wọn. Nítorínã, a ti dárúkọ gbogbo àwọn ìlú-nlá àwọn ará Lámánì inú èyítí nwọ́n bá ti ronúpìwàdà, tí nwọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òdodo; tí nwọ́n sì yípadà. Àti nísisìyí ó sì ṣe, tí ọba àti gbogbo àwọn tí a ti yí lọ́kàn padà ní ìfẹ́ láti ní orúkọ, èyítí a ó fi mọ̀ nwọ́n yàtọ̀ sí àwọn arákùnrin nwọn; nítorínã, ọba jíròrò pẹ̀lú Áárọ́nì àti púpọ̀ nínú àwọn àlùfã nwọn, lórí orúkọ tí nwọn yíò jẹ́, kí nwọ́n fi lè yàtọ̀. Ó sì ṣe tí nwọ́n pe orúkọ ara nwọn ní Kòṣe-Nífáì-Léhì; a sì nfi orúkọ yĩ pè nwọ́n, a kò sì pè nwọ́n ní àwọn ará Lámánì mọ́. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣiṣẹ́ tara251 tara; bẹ̃ni, nwọ́n sì bá àwọn ará Nífáì rẹ́pọ̀; nítorínã, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ pẹ̀lú nwọn, ègún Ọlọ́run kò sì tẹ̀lé wọn mọ́. 24 Àwọn ará Lámánì gbógun ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run—Àwọn Kòṣe-Nífáì-Léhì yọ̀ nínú Krístì, àwọn ángẹ́lì sì bẹ̀ nwọ́n wò—Nwọ́n yàn láti kú ju pé kí nwọ́n dãbò bò ara nwọn—Nínú àwọn ará Lámánì tún yípadà síi. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí àwọn ará Ámálẹ́kì àti àwọn ará Ámúlónì àti àwọn ará Lámánì tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Ámúlónì, àti ní ilẹ̀ Hẹ́lámì pẹ̀lú, àti tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, ní kúkúrú, t í nwọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní àyíká, tí nwọn kò tĩ yípadà, tí nwọn kò sì tĩ jẹ́ orúkọ Kòṣe-Nífáì-Léhì, ni àwọn ará Ámálẹ́kì pẹ̀lú àwọn ará Ámúlónì rú sókè, ní ìrunú sí àwọn arákùnrin nwọn. Ìkórira nwọn sì pọ̀ púpọ̀ sí nwọn, àní tó bẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣọ̀tẹ̀ sí ọba nwọn, tó bẹ̃ tí nwọn kò fẹ́ kí ó jẹ́ ọba fún nwọn mọ́; nítorínã, nwọ́n kó ohun ìjà jọ sí àwọn Kòṣe-Nífáì-Léhì. Nísisìyí ọba gbé ìjọba rẹ̀ lé ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Kòṣe-Nífáì-Léhì. Ọba sì kú ní ọdún nã èyítí àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìmúrasílẹ̀ ogun láti kọlu àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Nísisìyí, nígbàtí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí nwọ́n ti jáde wá pẹ̀lú rẹ̀ rí gbogbo ìmúrasílẹ̀ tí àwọn ará Lámánì ti ṣe láti pa àwọn arákùnrin nwọn, nwọ́n kọjá lọ sí ilẹ̀ Mídíánì, níbẹ̀ sì ni Ámọ́nì bá gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ pàdé; tí nwọ́n sì ti ibẹ̀ wá sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, láti lè ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú Lámónì àti pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀ Kòṣe-Nífáì-Léhì, ohun tí nwọn yíò ṣe láti dãbò bò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì. Nísisìyí kò sí ẹ̀yọ ẹnìkan nínú àwọn ènìyàn nã èyítí a ti yí lọ́kàn padà sọ́dọ̀ Olúwa tí yíò gbé ohun ìjà ti arákùnrin nwọn; rárá, nwọn kò tilẹ̀ ní ṣe ìpalẹ̀mọ́ kankan fún ogun; bẹ̃ni, ọba nwọn pẹ̀lú pàṣẹ fún nwọn láti má ṣe eleyĩ. Nísisìyí, àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí ó bá àwọn ènìyàn nã sọ nípa ọ̀rọ̀ nã: Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi, ẹ̀yin ènìyàn àyànfẹ́ mi, pé Ọlọ́run wa tí ó tóbi, nínú dídára rẹ̀ ran àwọn arákùnrin wa yĩ, àwọn ará Nífáì, sì wá láti wãsù fún wa, àti láti yí wa lọ́kàn padà kúrò nínú àwọn àṣà àwọn bàbá búburú wa. Sì kíyèsĩ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi tí ó tóbi, pé ó ti fún wa ní Ẹ̀mí rẹ̀ láti dẹ ọkàn wa, tí àwa sì ti ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin yĩ, àwọn ará Nífáì. Sì kíyèsĩ, mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi, pé nípa ìrẹ́pọ̀ yĩ, àwa ti yí ọkàn padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa, pẹ̀lú àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpànìyàn tí àwa ti ṣe. Èmi sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi, bẹ̃ni, Ọlọ́run mi tí ó tóbi, pé ó ti yọ̣́da wa láti ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ohun wọ̀nyí, àti pé ó ti dáríjì wá lórí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ àti ìpànìyàn tí a dá, tí ó sì ti múẹ̀bi kúrò lọ́kàn wa, nípasẹ̀ ìtóyè Ọmọ rẹ̀. Àti nísisìyí kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, níwọ̀n ìgbàtí ó ti jẹ́ ohun tí ó yẹ kí àwa ó ṣe (nítorípé àwa ni a kùnà jù nínú gbogbo ènìyàn) láti ronúpìwàdà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa àti gbogbo ìpànìyàn tí àwa ti ṣe, kí àwa kí ó sì jẹ́ kí Ọlọ́run yọ eleyĩ kúrò lọ́kàn wa, nítorípé èyí ni ohun tí ó tọ́ fún wa láti ṣe, pé kí àwa kí ó ronúpìwàdà pátápátá níwájú Ọlọ́run, kí ó lè mú àbàwọ́n wa kúrò— Nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n jùlọ, níwọ̀n ìgbàtí Ọlọ́run ti mú àwọn àbàwọ́n wa kúrò, tí àwọn idà wa sì ti mọ́, nítorínã, ẹ jẹ́ kí a dẹ́kun fífi ẹ̀jẹ́ àwọn arákùnrin wa ṣe àbàwọ́n fún idà wa. Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún nyín, rárá, ẹ jẹ́ kí a pa idà wa mọ́ kúrò lọ́wọ́ àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin wa; nítorípé bóyá, bí àwa bá tún fi àbàwọ́n bá idà wa, nwọn kò ní di wíwẹ̀mọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Ọmọ Ọlọ́run wa tí ó tóbi; èyítí yíò ta sílẹ̀ fún ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ọlọ́run tí ó tóbi nã sì ti ṣãnú fún wa, ó sì ti fi àwọn ohun wọ̀nyí yé wa kí àwa má bã ṣègbé; bẹ̃ni, òun sì ti sọ àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀ fún wa ní ìṣãjú, nítorítí ó fẹ́ràn ẹ̀mí wa gẹ́gẹ́bí ó ti fẹ́ràn àwọn ọmọ wa; nítorínã, nínú ãnú rẹ̀ ni ó nbẹ̀wá wò nípasẹ̀ àwọn ángẹ́lì rẹ̀, pé kí ìlànà ìgbàlà nã lè di mímọ̀ fún wa àti fún àwọn ìran tí nbọ̀ lẹ́hìn ọ̀la. Áà, báwo ni ãnú Ọlọ́run wa ti tó! Àti nísisìyí kíyèsĩ, nígbàtí àwa ti ṣe èyí láti mú àbàwọ́n kúrò lára wa, tí a sì ti mú idà wa mọ, ẹ jẹ́ kí a fi nwọ́n pamọ́, kí nwọ́n bá lè wà ní mímọ́, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí sí Ọlọ́run wa ní ọjọ́ ìkẹhìn, tàbí ní ọjọ́ tí a ó mú wa dúró níwájú rẹ̀ fún ìdájọ́, pé àwa kò fi àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin wa bá idà wa láti ìgbà nã tí ó ti kọ́ wa ní ọ̀rọ̀ rẹ, tí òun sì ti mú wa mọ nípasẹ̀ èyí. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, bí àwọn arákùnrin wa bá lépa láti pa wá run, ẹ kíyèsĩ, àwa yíò fi idà wa pamọ́, bẹ̃ni, àní àwa yíò rì nwọ́n mọ́lẹ̀, kí nwọn lè wà ní mímọ́, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí pé àwa kò lò nwọ́n rí, ní ọjọ́ ìkẹhìn; bí àwọn arákùnrin wa bá sì pa wá run, ẹ kíyèsĩ, àwa yíò lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, a ó sì yè. Àti nísisìyí, ó sì ṣe nígbàtí ọba ti parí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí gbogbo àwọn ènìyàn nã sì péjọ, nwọ́n kó idà nwọn, pẹ̀lú gbogbo ohun ìjà nwọn èyítí nwọn ti lò fún títa ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, nwọ́n sì rì nwọ́n mọ́lẹ̀ pátápátá. Èyí ni nwọ́n sì ṣe, nítorípé lọ́kàn nwọn, èyí jẹ́ ẹ̀rí sí Ọlọ́run, àti sí ènìyàn pẹ̀lú, pé nwọn kò ní lo ohun ìjà mọ́ láéláé fún ìtàjẹ̀ ènìyàn sílẹ̀ mọ́; nwọ́n sì ṣe èyí, ní ìpinnu àti májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, pé kàkà kí nwọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin nwọn sílẹ̀, nwọn yíò fi ẹ̀mí ara nwọn lélẹ̀; àti pé kàkà kí nwọ́n gba ti ọmọnìkejì ẹni, nwọn yíò fún un; àti pé kàkà kí nwọ́n gbé ìgbé ayé ọ̀lẹ, nwọn yíò ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ nwọn. Báyĩ, àwa ríi pé, nígbàtí àwọn ará Lámánì yíi ti gbàgbọ́ tí nwọn sì ti mọ ọ̀títọ́, nwọ́n dúró ṣinṣin, nwọn yíò sì faradà ìyà àní títí fi dé ojú ikú kàkà kínwọ́n gbẹ̀ṣẹ̀; báyĩ ni àwa sì ríi pé nwọ́n ri ohun ìjà nwọn mọ́lẹ̀ fún àlãfíà, tàbí pé nwọ́n ri àwọn ohun ìjà ogun, nítorí àlãfíà. Ó sì ṣe tí àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì, ṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun, tí nwọ́n sì kọjá wá sí ilẹ̀ Nífáì láti pa ọba run, àti láti fi ẹlòmíràn rọ́pò rẹ̀, àti láti pa àwọn ènìyàn Kòṣe-Nífáì-Léhì run kúrò lórí ilẹ̀ nã. Nísisìyí nígbàtí àwọn ènìyàn nã rí i pé nwọn nbọ̀wá láti gbógun tì nwọ́n, nwọ́n jáde láti lọ pàdé nwọn, nwọ́n sì wólẹ̀ níwájú nwọn lórí ilẹ̀, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Olúwa; ipò yĩ ni nwọ́n sì wà nígbàtí àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí kọlũ nwọ́n, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n pẹ̀lú idà. Báyĩ sì ni ó rí láìrí àtakò, tí nwọ́n pa ẹgbẹ̀rún àti mãrún nínú nwọn; àwa sì mọ̀ pé nwọ́n jẹ́ alábùkún-fún, nítorítí nwọ́n ti lọ gbé pẹ̀lú Ọlọ́run nwọn. Nísisìyí nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé àwọn arákùnrin nwọn kọ̀ láti sá fún idà, tàbí pé kí nwọ́n yí sí ọ̀tún tàbí sí òsì, ṣùgbọ́n pé nwọn ndùbúlẹ̀, nwọn sì nparun, tí nwọ́n sì nyin Ọlọ́run àní bí nwọ́n ṣe nparun lọ́wọ́ idà— Nísisìyí, nígbàtí àwọn ará Lámánì rí èyí, nwọ́n dá ara nwọn lẹ́kun láti má pa nwọ́n; àwọn tí ọkàn nwọn sì ti dàrú nínú nwọn fún àwọn arákùnrin nwọn tí nwọ́n ti parun nípasẹ̀ idà sì pọ̀, nítorítí nwọ́n ronúpìwàdà fún àwọn ohun tí nwọ́n ti ṣe. Ó sì ṣe tí nwọ́n da àwọn ohun ìjà ogun nwọn sílẹ̀, tí nwọn kò sì gbé nwọn mọ, nítorítí ìrora bá nwọn fún gbogbo ìpànìyàn tí nwọ́n ti ṣe; nwọn sì wólẹ̀, àní gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin nwọn, tí nwọ́n sì nwojú ãnú àwọn tí nwọ́n gbọ́wọ́ sókè láti pa nwọ́n. Ó sì ṣe tí àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ọjọ́ nã ju iye àwọn tí nwọ́n ti pa; àwọn tí nwọ́n sì ti pa jẹ́ olódodo ènìyàn, nítorínã, àwa kò ní ìdí kan láti ṣiyèméjì pé a ti gbà nwọ́n là. Kò sì sí ẹni búburú kan nínú àwọn tí nwọ́n pa; ṣùgbọ́n àwọn tí a mú wá sí ìmọ̀ òdodo ju ẹgbẹ̀rún lọ; báyĩ ni àwa ríi pé Ọlọ́run nṣiṣẹ́ ní oríṣiríṣi ọ̀nà fún ìgbàlà àwọn ènìyàn rẹ̀. Nísisìyí àwọn ará Ámálẹ́kì àti àwọn ará Ámúlónì ni ó pọ̀ jù nínú àwọn ará Lámánì tí ó pa àwọn arákùnrin wọn lọ́pọ̀lọpọ̀, púpọ̀ nínú nwọn sì jẹ́ ti ipa àwọn Néhórì. Nísisìyí, nínú àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Olúwa, kò sí àwọn ará Ámálẹ́kì tàbí àwọn ará Ámúlónì, tàbí èyí tí í ṣe ti ipa Néhórì, ṣùgbọ́n ìran Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì ni nwọn íṣe. Báyĩ sì ni àwa mọ̀ dájúdájú pé lẹ́hìn tí a bá ti fún àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ nípa Ẹ̀mí-Ọlọ́run lẹ̃kan, tí nwọ́n sì ti ní ìmọ̀ nlá nípa èyítí í ṣe ti òdodo, tí nwọ́n sì ti ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwàìrékọjá, nwọn yíò burú síi, nípa èyí, ipò nwọn yíò burú jù bí èyítí nwọn kò mọ ohun wọ̀nyí rí. 25 Ìwà-ìfinràn àwọn ará Lámánì ńtànkálẹ̀ síi—Àwọn irú-ọmọ àwọnàlùfã Nóà ṣègbé gẹ́gẹ́bí Ábínádì ti sọtẹ́lẹ̀—Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará Lámánì ni a yí lọ́kàn padà tí nwọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn Kòṣe-Nífáì-Léhì—Nwọ́n gba Krístì gbọ́, nwọ́n sì pa òfin Mósè mọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa. Sì kíyèsĩ, báyĩ ni ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì nì bínú púpọ̀ si nítorítí nwọ́n pa àwọn arákùnrin nwọn; nítorínã nwọ́n ṣe ìbúra láti gbẹ̀san lára àwọn ará Nífáì; nwọn kò sì gbìyànjú láti pa àwọn ará Kòṣe-Nífáì-Léhì mọ́ nígbà nã. Ṣùgbọ́n nwọ́n kó àwọn ọmọ ogun nwọn, nwọ́n sì kọjá lọ sínú ibi agbègbè ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nwọ́n sì kọlũ àwọn ènìyàn tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Amonáíhà nwọ́n sì pa nwọ́n run. Lẹ́hìn èyí nnì, nwọ́n ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun pẹ̀lú àwọn ará Nífáì, nínú èyítí nwọ́n lé nwọn, tí nwọ́n sì pa nwọ́n. Nínú àwọn ará Lámánì tí nwọ́n sì pa ni ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn irú-ọmọ Ámúlónì wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, tí nwọ́n jẹ́ àlùfã fún Nóà, àwọn nã ní a sì pa nípasẹ̀ ọwọ́ àwọn ará Nífáì; Àwọn tí ó sì kù, lẹ́hìn tí nwọ́n ti sá lọ sínú aginjù tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn, tí nwọ́n sì ti gba agbára àti àṣẹ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì, kí nwọ́n pa púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì nã run pẹ̀lú iná nítorí ìgbàgbọ́ nwọn— Nítorítí púpọ̀ nínú nwọn, lẹ́hìn tí nwọ́n ti pàdánù ohun púpọ̀, tí nwọ́n sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú, bẹ̀rẹ̀sí rú sókè ní ìrántí àwọn ọ̀rọ̀ tí Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ti wãsù fún nwọn ní ilẹ̀ nwọn; nítorínã, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣe àìgbàgbọ́ sí gbogbo àwọn àṣà bàbá nwọn, tí nwọ́n sì gba Olúwa gbọ́, àti pé òun ni ó fún àwọn ará Nífáì ní agbára títóbi; báyĩ sì ni a yí púpọ̀ nínú nwọn lọ́kàn padà nínú aginjù nã. Ó sì ṣe tí àwọn olórí nnì, tí nwọn jẹ́ ìyókù àwọn ọmọ Ámúlónì mú kí a pa nwọ́n, bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú ohun wọ̀nyí. Nísisìyí, ikú-ajẹ́rĩkú yí mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin nwọn ru sókè ní ìbínú; ìjà sì bẹ̀rẹ̀ nínú aginjù; àwọn ará Lámánì sì bẹ̀rẹ̀sí lépa ẹ̀mí àwọn irú-ọmọ Ámúlónì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n; nwọ́n sì sá wọ inú aginjù èyítí ó wà ní apá ìlà-oòrùn. Sì kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì nlépa ẹ̀mí nwọn títí di òní. Báyĩ sì ni ọ̀rọ̀ Ábínádì ṣẹ, èyítí ó sọ nípa irú-ọmọ àwọn àlùfã nnì tí nwọ́n ṣe é tí ó fi kú nípasẹ̀ iná. Nítorítí ó wí fún nwọn pé: Ohun tí ẹ̀yin yíò ṣe fún mi yíò jẹ́ ẹ̀yà irú ohun tí nbọ̀. Àti nísisìyí Ábínádì ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kú nípasẹ̀ iná nítorí ìgbàgbọ́ tí ó ní nínú Ọlọ́run; báyĩ, èyí ni ìtumọ̀ ohun tí ó sọ, pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò kú nípasẹ̀ iná, gẹ́gẹ́bí ó ti rí fún òun. Ó sì wí fún àwọn àlùfã Nóà pé irú-ọmọ nwọn yíò mú kí á pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ gẹ́gẹ́bí a ṣe pa òun, àti pé a ó fọ́n nwọn ká ilẹ̀ òkẽrè, a ó sì pa nwọ́n, àní bí ẹranko búburú ṣe nlé àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ tí sì pa; àti nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣẹ, nítorítíàwọn ará Lámánì lé nwọn, nwọ́n sì dọdẹ nwọn, nwọ́n sì pa nwọ́n. Ó sì ṣe, nígbàtí àwọn ará Lámánì r í i pé nwọn kò lè borí àwọn ará Nífáì, nwọ́n tún padà lọ sí ilẹ̀ nwọn; ọ̀pọ̀lọpọ̀ nwọn sì kọjá sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì láti gbé inú rẹ̀ àti ilẹ̀ Nífáì, nwọ́n sì da ara nwọn pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, tí nwọ́n íṣe ará Kòṣe-Nífáì-Léhì. Àwọn nã sì ri àwọn ohun ìjà-ogun nwọn mọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin nwọn ti ṣe, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí jẹ́ ènìyàn rere; tí nwọ́n sì rìn ní ọ̀nà Olúwa, tí nwọ́n sì gbiyanju láti pa àwọn òfin àti àwọn ilana rẹ̀ mọ́. Bẹ̃ni, nwọ́n sì pa òfin Mósè mọ́; nítorípé ó tọ́ pé kí nwọ́n sì máa pa òfin Mósè mọ́ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ síbẹ̀, nítorítí a kò tĩ múu ṣẹ tán. Ṣùgbọ́n l’áìṣírò òfin Mósè, nwọ́n ṣã fojúsọ́nà sì bíbọ̀ Krístì, nítorípé nwọ́n ka òfin Mósè sí ẹ̀yà bíbọ̀ rẹ, nwọ́n sì gbàgbọ́ pé nwọ́n níláti pa àwọn ohun wọnnì mọ́, èyítí o hán sí gbangba, títí di àkokò nã tí a ó fihàn sí nwọ́n. Nísisìyí kĩ ṣe pé nwọn rò pé nípa òfin Mósè ní ìgbàlà ṣe wà; ṣùgbọ́n pé òfin Mósè dúró fún èyítí yíò mú ìgbàgbọ́ nwọn nínú Krístì dúró ṣinṣin; báyĩ ni nwọ́n sì gba ìrètí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, sí ìgbàlà ayérayé, tí nwọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀, tí ó nsọ nípa àwọn ohun èyítí nbọ̀. Àti nísisìyí kíyèsĩ, Ámọ́nì, àti Áárọ́nì, àti Òmnérì, àti Hímnì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn yọ̀ púpọ̀púpọ̀, fún àṣeyọrí tí nwọ́n ní lãrín àwọn ará Lámánì, nítorítí nwọ́n ríi pé Olúwa ti gbọ́ àdúrà nwọn, àti pé ó ti jẹ́rĩ sí òtítọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí nwọn ní gbogbo ọ̀nà. 26 Ámọ́nì ṣògo nínú Olúwa—Olúwa nfi agbára fún àwọn olódodo, ó sì nfún nwọn ní ìmọ̀—Nípa ìgbàgbọ́ ènìyàn lè mú ẹgbẽgbẹ̀rún ọkàn wá sí ìrònúpìwàdà—Ọlọ́run ní gbogbo agbára, ohun gbogbo ni ó sì yée. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ Ámọ́nì sí àwọn arákùnrin rẹ̀, tí ó wí báyĩ: Ẹ̀yin ará àti ẹ̀yin arákùnrin mi, kíyèsĩ mo wí fún un yín, báwo ni ìdí rẹ ti pọ̀ tó fún ayọ̀ wa; nítorípé njẹ́ àwa lè rọ́ pé Ọlọ́run lè fún wa ní ìbùkún nlá báyĩ nígbàtí a tẹ síwájú kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà? Àti nísisìyí, èmí bẽrè, irú ìbùkún nlá wo ni ó ti fi lé wa lórí? Njẹ́ ẹ̀yin lè sọọ́? Ẹ kíyèsĩ, èmi ṣe ìdáhùn rẹ̀ fún un yín, nítorítí àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì, wà nínú òkùnkùn, bẹ̃ni, àní nínú ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn jùlọ, ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, melo wọn ni a mú wá láti rí ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run tí ó yanilẹ́nu! Èyí sì jẹ́ ìbùkún tí a ti fi lé wa lórí, pé a ti jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run láti ṣe iṣẹ́ nlá yĩ. Ẹ kíyèsĩ, ẹgbẹ̃gbẹ̀rún nwọ́n ní ó yọ̀, tí a sì ti mú wá sí inú agbo Ọlọ́run. Ẹ kíyèsĩ, àkokò ti tó fún ìkórè, alábùkún-fún sì ni ẹ̀yin í ṣe, nítorítí ẹ̀yin ti tẹ dòjé nyín bọ ìkórè, ẹ̀yin sì kórè pẹ̀lú agbára nyín, bẹ̃ni, ní gbogbo ọjọ́ niẹ̀yin nṣiṣẹ́; ẹ sì kíyèsí iye ìtí nyín! A ó sì kó nwọn jọ sínú àká, kí nwọ́n má bã ṣòfò. Bẹ̃ni, ìjì kò ní lè tẹ̀ nwọ́n pa ní ọjọ́ ìkẹhìn; bẹ̃ni, afẹ́fẹ́ líle kò ní lè fà nwọn tu; ṣùgbọ́n nígbàtí ìjì yíò bá dé, a ó kó nwọn jọ sí ãyè nwọn, tí ìjì nã kò fi ní lè wọ ãrin nwọn; bẹ̃ni, ẹ̀fũfù líle kò ní lè gbé nwọn lọ sí ibi èyítí ó wù tí ọ̀tá fẹ́ gbé nwọn lọ. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nwọ́n wà ní ọwọ́ Olúwa ìkórè, tirẹ̀ ni nwọ́n sì íṣe; òun yíò sì jí nwọn dìde ní ọjọ́ ìkẹhìn. Ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run wa; ẹ jẹ́ kí a kọrin ìyìn rẹ̀, bẹ̃ni, ẹ jẹ́ kí a fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́, nítorítí ó nṣíṣẹ òdodo títí láéláé. Nítorípé bí kò bá ṣe pé àwa ti jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àwọn arákùnrin wa ọ̀wọ́n wọ̀nyí, tí nwọ́n fẹ́ràn wa lọ́pọ̀lọpọ̀, ìbá ṣì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkórira fún wa, bẹ̃ni nwọn yíò sì jẹ́ àjòjì sí Ọlọ́run síbẹ̀. Ó sì ṣe, nígbàtí Ámọ́nì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Áárọ́nì arákùnrin rẹ̀ bá a wí pé: Ámọ́nì, mo bẹ̀rù pé kí ayọ̀ rẹ má já sí ìyangàn. Ṣugbọ́n Ámọ́nì wí fún un: èmi kò yangàn nínú agbára mi, tàbí nínú ọgbọ́n mi; ṣùgbọ́n, kíyèsĩ, ayọ̀ mi kún, bẹ̃ni, ọkàn mi kún rẹ́rẹ́ fún ayọ̀, èmi yíò sì yọ̀ nínú Ọlọ́run mi. Bẹ̃ni, èmi mọ̀ pé èmi kò jẹ́ nkan; nípa ti agbára mi, aláìlera ni èmi í ṣe; nítorínã, èmi kò ní yangàn nípa ara mi, ṣùgbọ́n èmi yíò yangàn nípa Ọlọ́run mi, nítorípé nípasẹ̀ agbára rẹ̀ èmi lè ṣe ohun gbogbo; bẹ̃ni, kíyèsĩ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu nlá-nlà ni àwa ti ṣe ní ilẹ̀ yĩ, fún èyí tí àwa yíò yin orúkọ rẹ̀ láéláé. Ẹ kíyèsĩ, ẹgbẹ̃gbẹ̀rún mélo nínú àwọn arákùnrin wa ni ó ti tú sílẹ̀ kúrò nínú oró ipò-òkú; tí a sì mú nwọn kọ orin ìfẹ́ ìdãndè, èyí yĩ sì rí bẹ̃ nítorí agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀ èyítí ó wà nínú wa, nítorínã njẹ́ àwa kò ha ní ìdí nlá láti yọ̀? Bẹ̃ni, àwa ni ìdí láti yìn ín títí láéláé, nítorítí òun ni Ọlọ́run Tí Ó Ga Jùlọ, ó sì ti tú àwọn arákùnrin wa sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n ọ̀run àpãdì. Bẹ̃ni, òkùnkùn ayérayé àti ìparun ni ó yí nwọn ká; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, òun ti mú nwọn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ títí ayé, bẹ̃ni, sínú ìgbàlà títí ayé; à sì yí nwọn ká pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́; bẹ̃ni, àwa sì jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ rẹ̀ ní ṣíṣe ohun ìyanu nlá yĩ. Nítorínã, ẹ jẹ́ kí àwa ṣògo, bẹ̃ni, àwa yíò ṣògo nínú Olúwa; bẹ̃ni, àwa yíò yọ̀, nítorítí ayọ̀ wa kún; bẹ̃ni, àwa yíò yin Ọlọ́run wa títí láéláé. Kíyèsĩ, tani ó lè ṣògo àṣejù nínú Olúwa? Bẹ̃ni, tani ó lè sọ àsọjù nípa agbára nlá rẹ, àti ãnú rẹ̀, àti ìpamọ́ra rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn? Kíyèsĩ, mo wí fún un yín, èmi kò lè sọ díẹ̀ nínú bí èmi ti mọ̀ ọ́ lára mi. Tani ó ha lè rò pé Ọlọ́run wa yọ́ ní ãnú sí wa tóbẹ̃ láti já wá gbà kúrò nínú ipò búburú, ẹ́ṣẹ̀ àti àìmọ́. Kíyèsĩ, àwa jáde lọ àní nínú ìbínú, pẹ̀lú ìdẹ́rùbà nlá láti pa ìjọ rẹ̀ run. Nigbanã! kíni ìdí rẹ̀ tí òun kò fi sọ wá sínú ìparun búburú, bẹ̃ni, kíni òun kò ṣe jẹ́ kí idà àìṣègbè rẹ̀ ṣubú lù wá, kí ó sì sọ wá sínú ipò àìnírètí ayérayé? Àní, ẹ̀mí mi fẹ́rẹ̀ sá kúrò nínú àgọ́ ara yĩ fún irú èrò yĩ. Ẹ kíyèsĩ, òun kò ṣe àìṣègbè lé wa lórí, ṣùgbọ́n nínú ãnú rẹ tí ó ti pọ̀ púpọ̀, òun mú wa rékọjá lórí ọ̀gbun ayérayé ti ikú àti òṣì, àní sí ìgbàlà ọkàn wa. Àti nísisìyí kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, tani ẹni nã nípa ti ara tí ó lè mọ́ ohun wọ̀nyí? Mo wí fún nyín, kò sí ẹnìkan tí ó mọ́ ohun wọ̀nyí, àfi àwọn onírònúpìwàdà. Bẹ̃ni, ẹnití ó bá ronúpìwàdà tí ó sì lo ìgbàgbọ́, tí ó sì mú iṣẹ́ rere jáde wá, tí ó sì ngbàdúrà ní àìsìmì—àwọn wọ̀nyí ni a fún ní ànfàní láti mọ́ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run; bẹ̃ni, àwọn wọ̀nyí ni a ó fún ní ànfàní ìfihàn àwọn ohun tí a kò fihàn rí; bẹ̃ni, a ó sì fún àwọn wọ̀nyí ní ànfàní láti mú ẹgbẽgbẹ̀rún ọkàn wá sí ìrònúpìwàdà, àní bí a ti fi fún wa láti mú àwọn arákùnrin wa wọ̀nyí wá sí ìrònúpìwàdà. Nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, njẹ́ ẹ̀yin ha rántí pé àwa sọ fún àwọn arákùnrin wa ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, pé àwa yíò kọjá lọ sí ilẹ̀ Nífáì, láti wãsù sí àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì, tí nwọn sì fi wá rẹ̃rín ẹlẹ́yà? Nítorítí nwọ́n wí fún wa pé: Njẹ́ ẹ̀yin lérò pé ẹ lè mú àwọn ará Lámánì wá sí ìmọ̀ òtítọ́? Njẹ́ ẹ̀yin rò wípé ẹ lè yí àwọn ará Lámánì lọ́kàn padà lórí àìpé àṣà àwọn bàbá nwọn, bí nwọ́n ṣe jẹ́ ọlọ́rùn-líle ènìyàn tó nnì; tí ọkàn nwọn a máa yọ̀ nínú ìtàjẹ̀sílẹ̀; tí nwọ́n ti lo àkokò nwọn nínú àìṣedẽdé èyítí ó burú jùlọ; tí ọ̀nà nwọn sì ti jẹ́ ti olùrékọjá láti ìbẹ̀rẹ̀ wá? Nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀yin rántí pé báyĩ ni nwọ́n wí fún wa. Lẹ́hìnnã, nwọ́n tún wípé: Ẹ jẹ́ kí a gbé ogun tì nwọ́n, kí àwa kí ó lè pa nwọ́n run ati ìwà àìṣedẽdé nwọn kúrò lórí ilẹ̀ nã, kí nwọ́n má bã borí wa, kí nwọ́n sì pa wá run. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, wíwá sínú a g i n j ù wá k ĩ ṣ e l á t i p a àwọn arákùnrin wa run, ṣùgbọ́n pẹ̀lú èrò àti gba ọkàn díẹ̀ nínú nwọn là. Nísisìyí nígbàtí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn wa, tí a sì fẹ́ padà sẹ́hìn, ẹ kíyèsĩ, Olúwa tù wá nínú, ó sì wípé: Ẹ kọjá lọ sãrin àwọn arákùnrin nyín, àwọn ará Lámánì, kí ẹ sì faradà ìpọ́njú nyín pẹ̀lú sũrù, Èmi yíò sì fún nyín ní àṣeyọrí. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, àwa ti wá, àwa sì ti lọ lãrín nwọn; àwa sì ti faradà ìpọ́njú a sì ti faradà onírũrú àìní; bẹ̃ni, àwa ti rin ìrìnàjò láti ilé dé ilé, tí àwa sì gbíyèlé ãnú aráyé—kĩ ṣe lé ãnú aráyé nìkan, ṣùgbọ́n lé ãnú Ọlọ́run pẹ̀lú. Àwa sì ti wọ inú ilé nwọn, a sì kọ́ nwọn lẹ̃kọ́, àwa sì ti kọ́ nwọn ní ojú òpópó; bẹ̃ni, àwa ti kọ́ nwọn lórí àwọn òkè nwọn; àwa sì ti wọ inú tẹ́mpìlì nwọn pẹ̀lú, àti inú sínágọ́gù nwọn, a sì ti kọ́ nwọn lẹ́ẹkọ́; ṣùgbọ́n nwọ́n lé wa jáde, nwọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, nwọ́n sì tutọ́ sí wa lára, nwọn sì gbá wa lẹ́nu; nwọ́n sì tún sọ wá ní òkúta, tí nwọn sì dè wá pẹ̀lú okùn tí ó le, tí nwọ́n sì sọ wa sínú tũbú; ṣùgbọ́n nípaagbára àti ọgbọ́n Ọlọ́run a tún ti rí ìkóyọ. Àwa sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú, gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí sì rí bẹ̃ pé bóyá a lè ti ipasẹ̀ wa gba àwọn ọkàn díẹ̀ là; àwa sì lérò wípé ayọ̀ wa yíò kún bí a bá ti ipasẹ̀ wa gbà nínú nwọn là. Nísisìyí kíyèsĩ, àwa lè wò kí a sì rí èrè iṣẹ́ tí àwa ṣe; njẹ́ wọ́n ha kéré bí? Èmi wí fún un yín, rárá, ó pọ̀; bẹ̃ni, àwa sì lè ṣe ìjẹ́rĩ sí òtítọ́-inú nwọn, nítorí ìfẹ́ nwọ́n sí àwọn arákùnrin nwọn àti sí àwa nã pẹ̀lú. Nítorí ẹ sì kíyèsĩ ó sàn fún nwọn láti fi ẹ̀mí nwọn rúbọ ju kí nwọ́n gba ẹ̀mí ọ̀tá nwọn; nwọ́n sì ti ri àwọn ohun ìjà ogun nwọn mọ́ inú ilẹ̀, nítorí ìfẹ́ nwọn sí àwọn arákùnrin nwọn. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín, njẹ́ irú ìfẹ́ nlá báyĩ wà ní gbogbo ilẹ̀ yí rí? Ẹ kíyèsĩ, mò wí fún yín, Rárá, kò sí irú rẹ̀ rí, àní lãrín àwọn ará Nífáì. Nítorí kíyèsĩ, nwọn yíò gbé ohun ìjà sí àwọn arákùnrin nwọn; nwọn kò sì ní jẹ́ kí nwọn pa nwọ́n. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ iye àwọn tí nwọ́n ti fi ẹ̀mí nwọn lélẹ̀; àwa sì mọ̀ pé nwọ́n ti lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nwọn, nítorí ìfẹ́ tí nwọ́n ní àti ìkórira fún ẹ̀ṣẹ̀. Nísisìyí, njẹ́ àwa kò ha ní ìdí fún ayọ̀ bí? Bẹ̃ni, èmi wí fún yín, a kò rí irú ènìyàn bẹ̃ rí tí ó ní ìdí nlá irú èyí láti yọ̀ bí àwa, láti ìgbàtí ayé ti bẹ̀rẹ̀; bẹ̃ni, ayọ̀ mi sì pọ̀ púpọ̀, tó kí èmi fi yangan nínú Ọlọ́run mi; nítorítí ó ní gbogbo agbára, gbogbo ọgbọ́n, àti gbogbo òye; ohun gbogbo ni ó yée, òun sì jẹ́ Ẹni alãnú, àní sí ìgbàlà, fún àwọn tí yíò bá ronúpìwàdà, tí nwọ́n sì gba orúkọ rẹ̀ gbọ́. Nísisìyí tí eleyĩ bá sì íṣe ìyangàn, síbẹ̀ ni èmi yíò yangàn; nítorítí èyí ni ìyè àti ìmọ́lẹ̀ mi, ayọ̀ mi àti ìgbàlà mi, àti ìràpadà mi kúrò nínú ègbé ayérayé. Bẹ̃ni, ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run mi, ẹnití ó ti í ṣe ìrántí àwọn ènìyàn yĩ, tí í ṣe ẹ̀ka kan ti ìdílé Ísráẹ́lì, tí ó sì ti yapa kúrò lára rẹ̀ ní ilẹ̀ àjèjì; bẹ̃ni, mo wípé, alábùkún-fún ni orúkọ Ọlọ́run mi, ẹnití ó ṣe ìrántí wa, aṣákolọ nínú ilẹ̀ àjèjì. Nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi, àwa ríi pé Ọlọ́run a máa ṣe ìrántí ènìyàn gbogbo, ilẹ̀ èyíówù kí nwọ́n wà; bẹ̃ni, ó mọ́ iye àwọn ènìyàn rẹ̀, ọ̀pọ̀ ìyọ́nú rẹ̀ sì nbẹ lórí gbogbo aráyé. Nísisìyí, èyí ni ayọ̀ mi, àti ẹbọ ọpẹ́ nlá mi; bẹ̃ni, èmi yíò sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run mi títí láéláé. Àmín. 27 Olúwa pàṣẹ fún Ámọ́nì pé kí ó kó àwọn ará Kòṣe-Nífáì-Léhì lọ sí ibi àìléwu—Nígbàtí Ámọ́nì bá Álmà pàdé, ayọ̀ rẹ dáa lágara—Àwọn ará Nífáì fún àwọn ará Kòṣe-Nífáì-Léhì ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì—A sì npè nwọ́n ní awọn ènìyàn Ámọ́nì. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Lámánì nnì tí nwọ́n ti lọ jagun pẹ̀lú àwọn ará Nífáì ti ríi pé ohun asán ni láti wá ìparun fún nwọn lẹ́hìn tí nwọ́n ti gbìyànjú púpọ̀púpọ̀ láti pa nwọ́n run, nwọ́n tún padà lọ sí ilẹ̀ Nífáì. Ó sì ṣe tí àwọn ará Ámálẹ́kì bínú gidigidi, nítorí àdánù nwọnlójú ogun. Nígbàtí nwọ́n sì ríi pé nwọn kò lè gbẹ̀san lára àwọn ará Nífáì, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí rú àwọn ènìyàn nã sókè ní ìbínú sí àwọn arákùnrin wọn, àwọn ará Kòṣe-Nífáì-Léhì; nítorínã nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n run. Nísisìyí àwọn ènìyàn yí tún kọ̀ láti gbé ohun ìjà ogun nwọn, nwọ́n sì jọ̀wọ́ ara nwọn sílẹ̀ fún pípa ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-inú àwọn ọ̀tá nwọn. Nísisìyí nígbàtí Ámọ́nì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ rí iṣẹ́ ìparun yí lãrín àwọn tí wọ́n fẹ́ràn púpọ̀púpọ̀, àti lãrín àwọn tí ó fẹ́ràn nwọn púpọ̀púpọ̀—nítorítí nwọ́n hùwà sí nwọn bí pé ángẹ́lì tí Ọlọ́run rán sí nwọn láti gbà nwọ́n lọ́wọ́ ìparun ayérayé—nítorínã, nígbàtí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ rí iṣẹ́ ìparun nlá yĩ, nwọ kún fún ọ̀pọ̀ ãnú, nwọ́n sì wí fún ọba pé: Ẹ jẹ́ kí a kó àwọn ènìyàn Olúwa wọ̀nyí jọ, kí àwa sì kọjá lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wa àwọn ará Nífáì, kí àwa sì sálọ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, kí àwa má bá ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọba wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì yíò pa wá run, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà ìpànìyàn àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ èyítí àwa ti hù sí wọn. Ámọ́nì sì wípé: Èmi yíò lọ ṣe ìwádĩ lọ́dọ̀ Olúwa, bí òun bá sì sọ fún wa pé kí a kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wa, njẹ́ ẹ̀yin ó lọ bí? Ọba sì wí fún un pé: Bẹ̃ni, bí Olúwa bá wí fún wa pé kí a lọ, àwa yíò kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wa, àwa yíò sì jẹ́ ẹrú fún nwọn, títí àwa yíò fi ṣe àtúnṣe pẹ̀lú nwọn lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà ìpànìyàn àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ èyítí àwa ti hù sí nwọn. Ṣugbọ́n Ámọ́nì wí fún pé: Ó tako òfin àwọn arákùnrin wa, èyítí bàbá mi fi lẹ́lẹ̀, pé kí ẹrú ó wà lãrín nwọn; nítorínã, ẹ jẹ́ kí àwa ó kọjá lọ kí àwa sì gbẹ́kẹ̀lé ãnú àwọn arákùnrin wa. Ṣùgbọ́n ọba nã wí fún un pe: Wádĩ lọ́dọ̀ Olúwa, bí òun bá sì wí fún wa pé kí a lọ, àwa yíò lọ; bíkòjẹ́bẹ̃, àwa yíò ṣègbé ní ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe, tí Ámọ́nì lọ ó sì wádĩ lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa sì wí fún un pé: Kó àwọn ènìyàn yĩ jáde kúrò ní ilẹ̀ yĩ, kí nwọn má bã ṣègbé; nítorítí Sátánì ti gba ọkàn àwọn ará Ámálẹ́kì, tí nwọ́n nrú àwọn ará Lámánì lọ́kàn sókè ní ìbínú sí àwọn arákùnrin nwọn láti pa nwọ́n; nítorínã ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ yĩ; alábùkún-fún sì ni àwọn ènìyàn yĩ ní ìran yĩ, nítorítí èmi yíò pa nwọ́n mọ́. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Ámọ́nì lọ tí ó sì sọ fún ọba gbogbo ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ fún un. Nwọ́n sì kó gogbo àwọn ènìyàn nwọn jọ, bẹ̃ni, gbogbo àwọn ènìyàn Olúwa, nwọ́n sì kó gbogbo agbo àti ọ̀wọ́ ẹran nwọn jọ, nwọ́n sì jáde kúrò ní ilẹ̀ nã, nwọ́n sì dé inú aginjù èyítí ó pãlà ilẹ̀ Nífáì àti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nwọ́n sì bọ́ sí agbègbè ìhà ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí Ámọ́nì wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, èmi pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi yíò kọjá lọ sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ẹ̀yin yíò sí dúró níbíyĩ títí àwa ó fi padà wá; àwa yíò sì mọ̀ bí ọkàn àwọn arákùnrin wa ṣe rí, bí nwọ́n bání ìfẹ́ pé kí ẹ̀yin kí ó wọ inú ilẹ̀ nwọn. Ó sì ṣe bí Ámọ́nì ṣe nkọjá lọ sínú ilẹ̀ nã, tí òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pàdé Álmà, ní ibi èyítí a ti sọ nípa rẹ̀ ṣãjú; sì wọ́ ìpàdé ayọ̀ ni eleyĩ jẹ́. Nísisìyí ayọ̀ Ámọ́nì pọ̀ púpọ̀ tí ó kún rẹ́rẹ́; bẹ̃ ni, ayọ̀ nínú Ọlọ́run rẹ̀ gbée mì, àní títí ó fi dáa lágara; ó sì tún ṣubú lulẹ̀. Nísisìyí njẹ́ eleyĩ kĩ ṣe ayọ̀ tí ó tayọ bí? Ẹ kíyèsĩ, èyí ni ayọ̀ tí ẹnìkan kò lè rí gbà bíkòṣe onírònúpìwàdà tọ́tọ́ àti onírẹ̀lẹ̀ọkàn ènìyàn tíi lépa àlãfíà. Nísisìyí ayọ̀ Álmà pọ̀ púpọ̀ fún pípàdé àwọn arákùnrin rẹ̀, bákannã ni ayọ̀ Áárọ́nì, àti Òmnérì, àti Hímnì; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ayọ̀ nwọn kò tó láti tayọ agbára nwọn. Àti nísisìyí ó sì tún ṣe tí Álmà kó àwọn arákùnrin rẹ̀ padà lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; àní lọ sínú ilé rẹ̀. Nwọ́n sì lọ sọ fún adájọ́ àgbà àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí nwọn ní ilẹ̀ Nífáì, lãrín àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí adájọ́ àgbà nã fi ìkéde ránṣẹ́ jákè-jádò orílẹ̀-èdè nã, láti mọ́ ohùn àwọn ènìyàn nã nípa gbígba àwọn arákùnrin nwọn, tí nwọn í ṣe ará Kòṣe-Nífáì-Léhì. Ó sì ṣe tí ohùn àwọn ènìyàn nã dé, wípé: Kíyèsĩ, àwa yíò yọ̣́da ilẹ̀ nã ti Jẹ́ṣónì, èyítí ó wà ní apá ìlà-oòrùn lẹ́bã òkun, èyítí ó so mọ́ ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, èyítí ó wà ní apá gũsù ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀; ilẹ̀ Jẹ́ṣónì yĩ sì ni àwa yíò yọ̣́da fún àwọn arákùnrin wa fún ìjogún. Sì kíyèsĩ, àwa yíò fi àwọn ọmọ ogun wa sí ãrin ilẹ̀ Jẹ́ṣónì àti ilẹ̀ Nífáì kí àwa kí ó lè dãbò bò àwọn arákùnrin wa ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì; èyí ni àwa sì ṣe fún àwọn arákùnrin wa, nítorípé nwọ́n bẹ̀rù, láti gbé ohun-ìjà ogun ti àwọn arákùnrin nwọn kí nwọn má bã dẹ́ṣẹ̀; ẹ̀rù nlá nwọn yĩ sì nbẹ nítorí ìrònúpìwàdà púpọ̀ tí nwọ́n ní, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà ìpànìyàn àti ìwà búburú jọjọ tí nwọ́n ti hù. Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwa yíò ṣe èyí fún àwọn arákùnrin wa, kí nwọ́n lè jogún ilẹ̀ Jẹ́ṣónì; àwa yíò sì fi àwọn ọmọ ogun wa dãbò bò nwọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, bí nwọ́n bá ti lè fún wa nínú ohun ìní nwọn fún ìrànlọ́wọ́ fún wa láti lè tọ́jú àwọn ọmọ ogun wa. Nísisìyí, ó sì ṣe nígbàtí Ámọ́nì ti gbọ́ eleyĩ, ó padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Kòṣe-Nífáì-Léhì, àti Álmà pẹ̀lú rẹ̀, sínú aginjù, níbití nwọ́n ti pàgọ́ nwọn sí, nwọ́n sì sọ ohun gbogbo wọ̀nyí fún nwọn, Álmà sì tún sọ fún nwọn nípa ti ìyílọ́kànpadà rẹ̀, àti ti Ámọ́nì àti Áárọ́nì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó sì ṣe tí gbogbo nkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ayọ̀ nlá lãrín nwọn. Nwọ́n sì kọjá lọ sí ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, nwọ́n sì ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì nã ní ìní; àwọn ará Nífáì sì npè nwọ́n ní àwọn ènìyàn Ámọ́nì; nítorínã, orúkọ nã ni a fi mọ̀ nwọ́n láti ìgbà yĩ lọ. Nwọ́n sì wà lãrín àwọn ará Nífáì, a sì kà nwọ́n mọ́ àwọn ènìyàn tí í ṣe ti ìjọ-Ọlọ́run pẹ̀lú. A sì tún mọ̀ nwọ́n fún ìtara nwọn sí Ọlọ́run, àti sí ènìyàn; nítorítí nwọ́n jẹ́ olótĩtọ́ àtiẹni-dídúróṣinṣin nínú ohun gbogbo; nwọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ Krístì, àní títí dé òpin. Nwọ́n sì ka ìtàjẹ̀sílẹ̀ arákùnrin wọn sí ohun-ìkórira nlá; ẹnìkẹ́ni kò sì lè yí nwọn lọ́kàn padà láti gbé ohun-ìjà ogun ti àwọn ènìyàn wọn; nwọn kò sì ka ikú sí ohun ìbẹ̀rù rárá, nítorí ìrètí nwọn àti ìmọ̀ nwọn nípa Krístì àti àjĩnde; nítorínã, ikú ti di gbígbé mì fún nwọn nípasẹ̀ ìṣẹ́gun Krístì lórí rẹ̀. Nítorínã, nwọn yíò faradà ìyà ikú ní ọ̀nà tí ó pọ́n-ni-lójú àti èyítí ó burú jùlọ tí àwọn arákùnrin nwọn lè fi jẹ nwọ́n, kí nwọn ó tó gbé idà tàbí ohun-ìjà ogun míràn láti bá nwọn jà. Báyĩ ni ó sì rí, tí nwọ́n jẹ́ onítara ènìyàn àti ẹni-àyànfẹ́, tí nwọ́n sì rí ọ̀pọ̀ ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa. 28 A ṣẹ́gun àwọn ará Lámánì nínú ogun nlá kan—Ẹgbẹgbẹ̀rún ni a pa—Ìpín ènìyàn búburú ni ipò ìbànújẹ́ àìlópin; olódodo yíò sì gba ayọ̀ tí kò lópin. Ní ìwọ̀n ọdún 77 sí 76 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn tí àwọn ènìyàn Ámọ́nì ti gbilẹ̀ ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, tí a sì ti dá ìjọ kan sílẹ̀ ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, tí àwọn ọmọ ogun àwọn ará Nífáì sì ti yí ilẹ̀ Jẹ́ṣónì ká, bẹ̃ ni, ní gbogbo agbègbè tí ó yí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà ká; kíyèsĩ, àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì ti tẹ̀lé àwọn arákùnrin nwọn lọ sínú aginjù nã. Báyĩ sì ni ogun líle bẹ́ sílẹ̀; bẹ̃ni, àní irú èyítí a kò rí rí lãrín gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ti wà ní ilẹ̀ nã láti ìgbà tí Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù; bẹ̃ni, ẹgbẹgbẹ̀run àwọn ará Lámánì ni a sì pa, tí àwọn míràn sì fọ́nká sí ilẹ̀ òkẽrè. Bẹ̃ni, nwọ́n sì pa púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn Nífáì nã; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n lé àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì fọ́n nwọn ká, àwọn ènìyàn Nífáì sì tún padà lọ sí ilẹ̀ nwọn. Àti nísisìyí, àkokò yĩ sì jẹ́ èyítí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀fọ̀ pẹ̀lú ohùn-réré ẹkún gba ilẹ̀ nã jákè-jádò, lãrín àwọn ènìyàn Nífáì— Bẹ̃ni, igbe ẹkún àwọn opó tí nṣọ̀fọ̀ fún àwọn ọkọ nwọn, àti ti àwọn bàbá tí nwọn nṣọ̀fọ̀ fún àwọn ọmọ nwọn, àti ti ọmọbìnrin fún arákùnrin rẹ̀, bẹ̃ni, ti ọmọkùnrin fún bàbá rẹ̀; báyĩ sì ni igbe ẹkún ọ̀fọ̀ gba ãrin nwọn gbogbo, tí nwọn nṣọ̀fọ̀ fún àwọn ìbátan nwọn tí a ti pa. Àti nísisìyí, dájúdájú ọjọ́ ìbànújẹ́ ni èyí jẹ́; bẹ̃ni, àkokò ìrònú, àti àkokò fún ọ̀pọ̀ ãwẹ̀ àti àdúrà. Báyĩ sì ni ọdún kẹẹ̀dọ́gún ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin; Èyí sì ni ìtàn nípa Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, ìrìn-àjò nwọn ní ilẹ̀ Nífáì, ìyà tí ó jẹ nwọ́n ní ilẹ̀ nã, ìbànújẹ́ nwọn, àti ìpọ́njú nwọn, pẹ̀lú ayọ̀ nwọn tí kò lè yé ni, àti gbígbà àti ìdábòbò àwọn arákùnrin nã ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì. Àti nísisìyí kí Olúwa, tí í ṣe Olùràpadà gbogbo ènìyàn, bùkún ẹ̀mí nwọn títí láéláé. Eyĩ sì ni ìtàn nípa àwọn ogun àti ìjà lãrín àwọn ará Nífáì, àtiàwọn ogun lãrín àwọn ará Nífáì pẹ̀lú àwọn ará Lámánì; ọdún kẹẹ̀dọ́gún ìjọba àwọn onídàjọ́ sì dópin. Ní ãrín ọdún kíni sí ọdún kẹẹ̀dọ́gún sì ni ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ẹ̀mí parun; bẹ̃ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ búburú ni ó wáyé ní àkokò yĩ. Ẹgbẹgbẹ̀rún òkú ènìyàn ni a sì gbé sin sínú ilẹ̀, tí ẹgbẹ̃gbẹ̀rún òkú ènìyàn jẹrà lórí òkìtì lójú àgbáyé; bẹ̃ni, ẹgbẹ̃gbẹ̀rún sì nṣọ̀fọ̀ ìpàdánù àwọn ìbátan nwọn; nítorípé, gẹ́gẹ́bí Olúwa ti ṣe ìlérí, nwọ́n bẹ̀rù pé nwọn ti gba ìpín sí ipò ìbànújẹ́ àìlópin. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹgbẽgbẹ̀rún míràn nṣọ̀fọ̀ àdánù àwọn ìbátan nwọn nítọ́tọ́, síbẹ̀síbẹ̀, nwọ́n nyọ̀ nwọ́n sì nṣọ̀fọ̀ nínú ìrètí, àti pé nwọ́n mọ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn ìlérí Olúwa, pé a ó gbé nwọn dìde tí nwọn ó sì máa gbé ní apá ọ̀tún Ọlọ́run, nínú ipò ayọ̀ tí kò lópin. Báyĩ àwa sì ríi bí ipò aidọgba ènìyàn ṣe jẹ́ nípa ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá àti agbára èṣù, èyítí ó rí báyĩ nípa ọ̀nà àrékérekè tí ó ti pète rẹ̀ láti mú ọkàn ènìyàn nínú ìkẹkùn. Báyĩ ni àwa sì rí ìpè nlá nnì sí ìtẹramọ́ iṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà Olúwa; bayĩ ni àwa si rí ìdí nlá fún ìbànújẹ́, àti fún ayọ̀—ìbànújẹ́ nítorí ikú àti ìparun lãrín àwọn ènìyàn, àti ayọ̀ nítorí ìmọ́lẹ̀ Krístì sí ìyè. 29 Álmà fẹ́ láti kígbe ìpè ìrònúpìwàdà pẹ̀lú ìtara bí ti ángẹ́lì—Olúwa fún gbogbo orílẹ̀-èdè ní àwọn olùkọ́ni—Álmà ṣògo nínú iṣẹ́ Olúwa àti nínú àṣeyọrí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 76 kí a tó bí Olúwa wa. A! báwo ni ó ti wù mí tó kí èmi jẹ́ ángẹ́lì, ìba sì bá ìfẹ ọkàn mi mu kí èmi lè kọjá lọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú fèrè Ọlọ́run, àti ohùn tí yíò mi gbogbo ayé, kí èmi kí ó sì kígbe ìpè ìrònúpìwàdà sí ènìyàn gbogbo! Bẹ̃ni, èmi yíò kéde ìrònúpìwàdà àti ìlànà ìràpadà sí gbogbo ọkàn, bí sísán àrá, pé kí nwọ́n ronúpìwàdà, kí nwọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí ìbànújẹ́ má lè wà mọ́ ní orí ilẹ̀ àgbáyé. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ènìyàn ni èmi í ṣe, èmi sì ndẹ́ṣẹ̀ nínú ìfẹ́-inú mi; nítorípé ó yẹ kí èmi ní ìtẹ́lọ́rùn nínú àwọn ohun ti Olúwa ti ṣe fún mi. Kò tọ́ fún mi láti gbèrò nínú ìfẹ́-inú mi fún ìyípadà òfin Ọlọ́run tí ó tọ́, nítorítí èmi mọ̀ pé òun a máa ṣe fún ènìyàn gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú wọn yálà sí ti ikú tàbí ti ìyè; bẹ̃ ni, èmi mọ̀ pé òun a máa ṣe fún ènìyàn, bẹ̃ni, ó fún nwọn ní àwọn òfin tí a kò le yípadà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-inú nwọn, yálà sí ti ìgbàlà, tàbí sí ti ìparun. Bẹ̃ni, èmi mọ̀ wípé ohun dáradára àti ohun búburú ti wá níwájú gbogbo ènìyàn; ẹnití kò bá dá èyítí ó dára mọ̀ kúrò lára èyítí ó burú kò lẹ́bi; ṣùgbọ́n ẹnití ó bá mọ́ èyítí ó dára àti èyítí ó burú, òun ni a ó fun gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ̀, bóyá ó fẹ́ dáradára tàbí búburú, ìyè tàbí ikú, ayọ̀ tàbí ẹ̀dùn ọkàn. Nísisìyí, nígbàtí èmi sì ti mọ́ ohun wọ̀nyí, kíni èmi ṣe tún fẹ́ láti ṣe ju iṣẹ́ èyítí a ti pè mí fún? Kíni èmi ṣe fẹ́ láti jẹ́ ángẹ́lì, kí èmi lè sọ̀rọ̀ dé gbogbo ikangun áyé? Nítorí kíyèsĩ, Olúwa a máa fún gbogbo orílẹ̀-èdè, ní ti orílẹ̀èdè ati èdè tiwọn, fún kíkọ́ni ní ọ̀rọ̀ rẹ̀, bẹ̃ni, nínú ọgbọ́n, gbogbo àwọn ohun èyítí ó ríi pé ó tọ́ kí nwọn ní; nítorínã àwa ríi pé Olúwa a máa gbani níyànjú nínú ọgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú èyítí ó tọ́ tí ó sì jẹ́ òtítọ́. Èmi mọ́ ohun èyítí Olúwa ti pa láṣẹ fún mi, èmi sì ṣògo nínú rẹ̀. Èmi kò ṣògo nínú ara mi, ṣùgbọ́n èmi ṣògo nínú ohun èyítí Olúwa ti pa láṣẹ fún mi; bẹ̃ni, èyí sì ni ògo mi, pé bóyá èmi lè jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run láti mú ọkàn àwọn díẹ̀ wá sí ìrònúpìwàdà; èyí sì ni ayọ̀ mi. Sì kíyèsĩ, nígbàtí mo bá rí púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin mi pé nwọ́n ti ronúpìwàdà nítoótọ́, tí nwọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn, ìgbàyĩ ni ọkàn mi kún fún ayọ̀; tí èmi sì rántí ohun tí Olúwa ti ṣe fún mi, bẹ̃ni, àní tí ó ti gbọ́ àdúrà mi, bẹ̃ni, ìgbànã ni èmi rántí ọwọ́ ãnú rẹ̀ èyítí ó ti nà sí mi. Bẹ̃ni, èmi sì tún rántí ìgbèkùn àwọn bàbá mi; nítorítí èmi mọ̀ dájú pé Olúwa ni ó gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú, nípa èyí ni ó sì ṣe dá ìjọ rẹ̀ sílẹ̀; bẹ̃ni, Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Ábráhámù, Ọlọ́run Ísãkì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù, tí ó sì gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú. Bẹ̃ni, gbogbo ìgbà ni èmi a máa rántí ìgbèkùn àwọn bàbá mi àti pẹ̀lú pé Ọlọ́run yĩ kannã tí ó gbà wọn lọ́wọ́ àwọn ará Égíptì, ni ó gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú. Bẹ̃ni, Ọlọ́run yĩ kannã ni ó sì dá ìjọ rẹ̀ sílẹ̀ lãrín nwọn; bẹ̃ni, Ọlọ́run yĩ kannã sì ni ó pè mí nípa ìpè mímọ́, láti kéde ọ̀rọ̀ nã sí àwọn ènìyàn yĩ, tí ó sì ti fún mi ní àṣeyọrí púpọ̀, nínú èyítí ayọ̀ mi kún. Ṣùgbọ́n, èmi kò yọ̀ nínú àṣeyọrí mi nìkan, ṣùgbọ́n ayọ̀ mi kún síi nítorí àṣeyọrí àwọn arákùnrin mi, tí nwọ́n ti lọ sí ilẹ̀ Nífáì. Kíyèsĩ, nwọ́n ti ṣiṣẹ́ púpọ̀, nwọ́n sì ti mú èso púpọ̀ jáde wá; báwo sì ni èrè nwọn yíò ti pọ̀ tó! Nísisìyí, nígbàtí mo bá ro ti àṣeyọrí àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí, a mu ọkan mi fo lọ ani bi i pe a pin niya kuro ní ara mi, bi o ti ri, bee si ni ayọ mí tobi to. Àti nísisìyí, kí Ọlọ́run kí ó sì jẹ́ kí àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí ní ànfàní láti jókọ́ nínú ìjọba Ọlọ́run; bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn tí nwọ́n jẹ́ èrè iṣẹ́ nwọn pẹ̀lú, pé kí nwọ́n má bã bọ́ sí ìta mọ́, ṣùgbọ́n kí nwọn máa yìn ín títí láéláé. Kí Ọlọ́run sì jẹ́ kí ó ṣẽṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, àní gẹ́gẹ́bí èmi ti sọ. Àmín. 30 Kòríhọ̀, ẹni aṣòdìsí-Krístì, nfi Krístì, Ètùtu, àti ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà—Ó nkọ́ni pé kò sí Ọlọ́run, pé kò sí ìṣubú ènìyàn, pé kò sí ìjìyà fún ẹ̀ṣẹ̀, àti pé kò sí Krístì—Álmà jẹ́rĩ pé Krístì yíò dé, àti pé ohun gbogbo fihàn pé Ọlọ́run kan nbẹ—Kòríhọ̀ bẽrè fún àmì kan ó sì ya odi—Èṣù ni ó ti farahàn Kòríhọ̀ ṣãjú gẹ́gẹ́bí ángẹ́lì, tí ó sì kọ́ ọ ní ohun tí yíò sọ—A tẹ Kòríhọ̀ mọ́lẹ̀, ó sì kú.Ní ìwọ̀n ọdún 76 sí 74 kí a tó bí Olúwa wa. Kíyèsĩ, báyĩ ni ó sì ṣe lẹ́hìn tí àwọn ènìyàn Ámọ́nì ti gbilẹ̀ lórí ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, bẹ̃ni, àti lẹ́hìn tí a ti lé àwọn ará Lámánì jáde kúrò lórí ilẹ̀ nã, tí àwọn ará ilẹ̀ nã sì ti gbé àwọn tí ó kú nínú nwọn sin— Nísisìyí nwọn kò ka àwọn tí ó kú nínú nwọn nítorípé iye nwọn pọ̀ tayọ; bẹ̃nã ni nwọn kò ka àwọn tí ó kú nínú àwọn ará Nífáì—ṣùgbọ́n ó sì ṣe lẹ́hìn tí wọn ti sin àwọn tí ó kú nínú nwọn tán, àti lẹ́hìn tí àwọn ọjọ́ ãwẹ̀ gbígbà, àti ọ̀fọ̀ ṣíṣe, àti àdúrà gbígbà ti rékọjá, (èyí tí íṣe ọdún kẹrìndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì) àlãfíà sì wà jákè-jádò orílẹ̀-èdè nã. Bẹ̃ni, àwọn ènìyàn nã sì gbiyanju láti pa òfin Olúwa mọ́; nwọ́n sì múná nínú ṣíṣe àwọn ìlànà Ọlọ́run, ní ìbámu pẹ̀lú òfin Mósè; nítorítí a ti kọ́ nwọn láti pa òfin Mósè mọ́ títí a ó fi múu ṣẹ. Báyĩ sì ni ó rí tí àwọn ènìyàn nã kò rí ìyọlẹ́nu kankan nínú gbogbo ọdún kẹrìndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì. Ó sì ṣe nínú ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹtàdínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́, tí àlãfíà sì wà títí. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe ní àkokò tí ọdún kẹtàdínlógún fẹ́rẹ̀ dópin, ọkùnrin kan wá sínú orílẹ̀-èdè Sarahẹ́múlà, ó sì jẹ́ Aṣòdìsí-Krístì, nítorítí ó bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí àwọn ènìyàn nã ní ìtakò àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlĩ ti sọ ṣãjú, nípa bíbọ̀ Krístì. Ní àkokò yĩ, kò sí òfin tí ó tako ìgbàgbọ́ ẹnìkẹ́ni; nítorítí ó jẹ́ ohun tí ó tako òfin Ọlọ́run pátápátá pé kí òfin kan wà èyítí yíò mú kí ẹlẹ́yà-mẹ̀yà wà lãrín àwọn ènìyàn. Nítorí báyĩ ni ìwé-mímọ́ wí: Ẹ yan ẹnití ẹ̀yin ó máa sìn ní òní. Nísisìyí, bí ẹnìkẹ́ni bá ní ìfẹ́ láti sin Ọlọ́run, ó jẹ́ ànfàní fun un; tàbí kí a wípé bí ó bá gba Ọlọ́run gbọ́ ó jẹ ànfàní fun un láti sìn ín; ṣùgbọ́n bí òun kò bá gbã gbọ́, kò sí òfin tí ó wípé kí a jẹẹ́ níyà. Ṣùgbọ́n bí ó bá pànìyàn, nwọn fi ìyà jẹ ẹ́ dé ojú ikú; bí ó bá sì fipá jalè, nwọn fi ìyà jẹẹ́ pẹ̀lú; bí ó bá sì jalè, nwọn jẹ̃ níyà pẹ̀lú; bí ó bá sì hu ìwà àgbèrè, nwọn jẹẹ́ níyà pẹ̀lú; bẹ̃ni, fún gbogbo ìwà búburú yĩ, nwọ́n jẹ nwọ́n níyà. Nítorítí òfin kan nbẹ pé a ó ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, kò sí òfin tí ó tako ìgbàgbọ́ ẹnìkẹ́ni; nítorínã, nwọn fi ìyà jẹ ènìyàn fún ìwà ìrúfin tí ó bá hù; nítorínã gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ ọgbọ̣́gba. Ẹni Aṣòdìsí-Krístì yĩ, èyítí orúkọ rẹ̀ íṣe Kòríhọ̀, (ti òfin kò sì lè dẽ) bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí àwọn ènìyàn nã pé kò sí Krístì kankan. Ní irú ọ̀nà báyĩ sì ni ó nwãsù, wípé: A!, ẹ̀yin tí a ti dè mọ́lẹ̀ nínú ìrètí aṣiwèrè àti asán, kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin fi àjàgà ohun aṣiwèrè wọ̀nyí kọ́ ọrùn ara nyín? Kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin fi nwá Krístì kan? Nítorípé kò sí ẹnìkẹ́ni tí ó lè mọ̀ nípa ohunkóhun tí nbọ̀wá. Kíyèsĩ, àwọn ohun wọ̀nyí tí ẹ̀yin npè ní àsọtẹ́lẹ̀, tí ẹ̀yin sọwípé àwọn wòlĩ mímọ́ ni ó gbé nwọn lée nyín lọ́wọ́, ẹ kíyèsĩ, àṣà aṣiwèrè àwọn bàbá nyin ni nwọ́n í ṣe. Báwo ni ẹ̀yin ṣe ní ìdánilójú lórí nwọn? Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin kò lè mọ̀ nípa àwọn ohun tí ẹ̀yin kò rí; nítorínã ẹ̀yin kò lè mọ̀ bí Krístì kan yíò bá wà. Ẹ̀yin ní ìrètí, tí ẹ sì wípé ẹ ó rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nyín. Ṣùgbọ́n, ẹ kíyèsĩ, àyọrísí ọkàn tí ó sínwín ni èyí í ṣe; ìdàrúdàpọ̀ ọkàn nyín yĩ sì débá nyín nítorí àṣà àwọn bàbá nyin, èyítí ó jẹ́ kí ẹ̀yin ó gba àwọn ohun tí kĩ ṣe òtítọ́ gbọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú àwọn ohun báyĩ ni ó sì sọ fún nwọn, tí ó wí fún nwọn pé kò lè sí ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n olúkúlùkù nínú ayé yĩ nṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni; nítorínã, ènìyàn ní ìlọ̀síwájú gẹ́gẹ́bí òye rẹ̀ ti tó, àti pé olúkúlùkù ènìyàn borí ní ìbámu pẹ̀lú agbára rẹ̀; àti pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú ohunkóhun tí ènìyàn ṣe. Báyĩ ni ó sì ṣe nwãsù fún nwọn, tí ó sì ndarí ọkàn púpọ̀ nínú nwọn kúrò, tí ó nmú wọn gbéraga nínú ipò ìwà búburú wọn, bẹ̃ni, tí ó sì ndarí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin, àti àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, láti hu ìwà àgbèrè—tí ó wí fún wọn pé bí ènìyàn bá ti kú òpin ayé ẹni nã ni èyí. Nísisìyí, ọkùnrin yĩ kọjá lọ sí orílè-èdè Jẹ́ṣónì pẹ̀lú, láti wãsù àwọn ohun wọ̀nyí lãrín àwọn ènìyàn Ámọ́nì, tí nwọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn ará Lámánì ní ìgbà kan rí. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nwọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n-ènìyàn jù púpọ̀ nínú àwọn ará Nífáì; nítorítí nwọ́n múu, nwọ́n sì dè é, nwọ́n sì gbé e wá sí iwájú Ámọ́nì, ẹnití í ṣe olórí àlùfã lórí àwọn ènìyàn nnì. Ó sì ṣe tí ó mú kí nwọ́n gbé e jáde kúrò lórí ilẹ̀ nã. Ó sì wá sí inú ilẹ̀ Gídéónì, ó sì bẹ̀rẹ̀sí wãsù fún àwọn nã pẹ̀lú; kò sì ní àṣeyọrí púpọ̀ ní ibi yĩ, nítorítí nwọ́n mú u nwọ́n sì dè é, nwọ́n sì gbé e lọ sí iwájú olórí àlùfã, tí í sì i ṣe adájọ́ àgbà lórí ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí olórí àlùfã nã sọ fún un pé: Kíni ìdí rẹ̀ tí ìwọ fi nkãkìri láti yí ọ̀nà Olúwa po? Kíni ìdí rẹ̀ tí ìwọ fi nkọ́ àwọn ènìyàn yì í pé kò ní sí Krístì, láti lè fi òpin sí ayọ̀ nwọn? Kíni ìdí rẹ̀ tí ìwọ fi nsọ̀rọ̀ tako gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wòlĩ mímọ́? Nísisìyí, orúkọ olórí àlùfã nã ni Gídónà. Kòríhọ̀ sì wí fún un pé: Nítorípé èmi kò kọ́ni ní àwọn àṣà aṣiwèrè àwọn bàbá rẹ, àti nítorípé èmi kò kọ́ àwọn ènìyàn yĩ pé kí nwọ́n de ara nwọn mọ́lẹ̀ lábẹ́ àwọn ìlànà àti ìṣe aláìgbọ́n, tí àwọn àlùfã ìgbà àtijọ́ gbé kalẹ̀, láti lè ní agbára àti àṣẹ lórí wọn, láti fi nwọ́n sí ipò àìmọ̀, kí nwọn má lè gbé orí wọn sókè, ṣùgbọ́n kí nwọ́n wà ní ipò ìtẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ. Ìwọ wípé àwọn ènìyàn yĩ jẹ́ òmìnira-ènìyàn. Kíyèsĩ, èmi wípé nwọ́n wà nínú oko-ẹrú. Ìwọ wípé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà nì jẹ́ òtítọ́. Kíyèsĩ, èmi wípé ìwọ kò mọ̀ pé òtítọ́ ni nwọ́n íṣe. Ìwọ wípé àwọn ènìyàn yìi jẹ́ ẹni-ìdálẹ́bi àti ẹni-ìṣubú ènìyàn, nítorí ìwà ìrékọjá òbí. Kíyèsĩ, èmi wípé ọmọ kò jẹ́ ẹni ìdálẹ́bi nítorí àwọn òbí rẹ̀. Ìwọ sì tún sọ wípé Krístì yíò wá. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi wípéìwọ kò mọ̀ pé Krístì kan yíò wà. Ìwọ sì tún sọ pẹ̀lú pé a ó pa á nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé— Báyĩ sì ni ìwọ ṣe darí àwọn ènìyàn yìi sí ipa àṣà àwọn bàbá rẹ, àti gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ; tí ìwọ sì tẹrí wọn bá, àní bí ẹnití ó wà nínú oko-ẹrú, kí ìwọ kí ó lè máa gbáyùnùn nínú lãlã nwọn, kí nwọ́n má lè gbé ojú sókè pẹ̀lú ìgboyà, àti kí nwọ́n má lè gbádùn ẹ̀tọ́ àti ànfãní tí í ṣe tiwọn. Bẹ̃ni, nwọn kò lè lo ohun tí í ṣe tiwọn, ní ìbẹ̀rù fún ṣíṣẹ̀ àwọn àlùfã nwọn, tí nwọn gbé àjàgà wọ̀ nwọ́n lọ́rùn gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú nwọn, tí nwọ́n sì ti mú nwọn gbàgbọ́, nípa àṣà nwọn, àti ìrètí nwọn, àti ìdùnnú nwọn, àti ìran rírí nwọn, àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ èké nwọn, pé bí wọn kò bá ṣe gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ wọn, wọn ṣẹ̀ sí ẹ̀dá àìmọ̀ kan, ẹnití nwọ́n sọ wípé í ṣe Ọlọ́run—ẹ̀dá tí ẹnìkẹ́ni kò rí rí tàbí tí ẹnìkẹ́ni kò mọ̀, tí kò sí rí, tí kò sì lè sí. Nísisìyí, nígbàtí olórí àlùfã àti adájọ́-àgbà rí líle ọkàn rẹ̀, bẹ̃ni, nígbàtí nwọn ríi pé yíò pẹ̀gàn Ọlọ́run pãpã, nwọn kò fèsì ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́; ṣùgbọ́n nwọ́n mú kí nwọ́n dè é; nwọ́n sì fi lé ọwọ́ àwọn olórí, nwọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, kí nwọ́n lè mú u wá síwájú Álmà, àti adájọ́-àgbà, ẹnití í ṣe bãlẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n mú u dé iwájú Álmà àti adájọ́-àgbà, ó tún tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́bí ó ti ṣe ní ilẹ̀ Gídéónì; bẹ̃ni, ó tẹ̀síwájú láti sọ̀rọ̀ búburú sí ohun mímọ́. Ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn líle níwájú Álmà, tí ó sì pẹ̀gàn àwọn àlùfã, àti àwọn olùkọ́ni, tí ó fẹ̀sùn kàn wọ́n pé àwọn ni ó ndarí àwọn ènìyàn nã lọ sí ipa ti àṣà òmùgọ̀ àwọn bàbá nwọn, láti lè máa gbáyùnùn nínú lãlã àwọn ènìyàn nã. Nísisìyí, Álmà wí fún un pé: Ìwọ mọ̀ pé àwa kò gbáyùnùn nínú lãlã àwọn ènìyàn yĩ; nítorí kíyèsĩ, èmi ti ṣe lãlã láti ìgbàtí ìjọba àwọn onídàjọ́ ti bẹ̀rẹ̀ títí dé àkokò yĩ, pẹ̀lú ọwọ́ ara mi fún ìrànlọ́wọ́ ara mi, l’áìṣírò ìrìnàjò mi púpọ̀ kãkiri orílẹ̀-èdè nã láti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn mi. Àti l’áìṣírò ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ lãlã tí èmi ti ṣe nínú ìjọ-onígbàgbọ́, èmi kò gba èrè ẹyọ owó kan rí fún iṣẹ́ lãlã mi; bákannã sì ni ẹnìkẹ́ni nínú àwọn arákùnrin mi, bíkòṣe lórí ìtẹ́ ìdájọ́; bẹ̃ sì ni àwa gbã ní ìbámu pẹ̀lú òfin lórí àkokò tí a bá lò tí a bá fi ṣe ìdájọ́. Àti nísisìyí, bí àwa kò bá gba ohunkóhun fún iṣẹ́ lãlã wa nínú ìjọ-onígbàgbọ́, kíni èrè wa fún iṣẹ́ lãlã tí àwa nṣe nínú ìjọ-onígbàgbọ́, bí kò bá ṣe pé láti kéde òtítọ́, kí àwa lè ní ìdùnnú nínú ayọ̀ àwọn arákùnrin wa? Nígbànã kíni ìdí rẹ tí ìwọ fi wípé àwa nwãsù fún àwọn ènìyàn yĩ láti rí èrè gbà, nígbàtí ìwọ tìkararẹ̀ mọ̀ wípé àwa kò gba èrè rárá? Àti nísisìyí, njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé àwa ntan àwọn ènìyàn yĩ, tí àwa sì nfún wọn ní ayọ̀ irú èyí ni ọkàn nwọn? Kòríhọ̀ sì dá a lóhùn wípé, Bẹ̃ni. Nígbànã ni Álmà wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan nbẹ? Ó sì dáhùn wípé: Rara. Nígbàyí ni Álmà wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ yíò tún sẹ́ pé Ọlọ́run kan nbẹ, àti pé ìwọ ó tún sẹ́ Krístì nã? Nítorí kíyèsĩ, èmi wí fún ọ, èmi mọ̀ pé Ọlọ́run kan nbẹ, àti pé Krístì yíò wá. Àti nísisìyí, ẹ̀rí wo ni ìwọ ní pé Ọlọ́run kò sí, tàbí pé Krístì kì yíò wá? Èmi wí fún ọ pé ìwọ kò ní, àfi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ nìkan. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, mo ní ohun gbogbo gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí pé àwọn nkan wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́; ìwọ pẹ̀lú sì ní àwọn nkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí sí ọ pé ọ̀títọ́ ni nwọ́n í ṣe; njẹ́ ìwọ yíò ha sẹ́ wọn bí? Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé otítọ́ ni àwọn nkan wọ̀nyí í ṣe? Kíyèsĩ, èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀mí irọ́-pípa wà nínú rẹ, ìwọ sì ti pa Ẹ̀mí Ọlọ́run tì, tí kò sì gbé inú rẹ mọ́; ṣùgbọ́n èṣù ni ó lágbára lórí rẹ, ó sì ndarí rẹ, tí ó sì nta ọgbọ́n àrékérekè láti pa àwọn ọmọ Ọlọ́run run. Àti nísisìyí Kòríhọ̀ wí fún Álmà pé: Bí ìwọ bá lè fi àmì kan hàn mí, ki emi le ni ìdánilójú pé Ọlọ́run kan wà, bẹ̃ni, fi hàn mí pé ó ní agbára, ìgbànã ni èmi yíò ní ìdánilójú nípa òtítọ́ ọ̀rọ̀ rẹ gbogbo. Ṣùgbọ́n Álmà wí fún un pé: Ìwọ ti rí àmì tó; ìwọ yíò ha dán Ọlọ́run rẹ wò bí? Njẹ́ ìwọ yíò wípé, fi àmì kan hàn mí, nígbàtí ìwọ ní ẹ̀rí gbogbo àwọn arákùnrin rẹ wọ̀nyí, àti gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ pẹ̀lú? Àwọn ìwé-mímọ́ hàn sí ọ kedere, bẹ̃ni, àti pẹ̀lú pé ohun gbogbo fi hàn pé Ọlọ́run kan nbẹ; bẹ̃ni àní ayé pẹ̀lú, àti ohun gbogbo tí ó wà lójú rẹ̀, bẹ̃ni, àti yíyí rẹ̀, bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn ogun ọ̀run pẹ̀lú tí nwọ́n sì nyí ni ipa ọ̀nà nwọn jẹ́ ẹ̀rí pé Ẹlẹ́dã Tí-ó-ga-jùlọ kan nbẹ. Síbẹ̀síbẹ̀ njẹ́ ìwọ kò ha lọ kákiri, tí ó sì ndarí ọkàn àwọn ènìyàn yĩ kúrò, tí ó njẹ́rĩ fún nwọn pé Ọlọ́run kò sí? Ẹ̀wẹ̀, njẹ́ ìwọ lè sẹ́ gbogbo ẹ̀rí wọ̀nyí? Ó sì wípé: Bẹ̃ni, èmi yíò sẹ́ ẹ, àfi bí ìwọ bá fi àmì kan hàn mí. Àti nísisìyí ó sì ṣe ti Álmà wí fún un pé: Kíyèsĩ, inú mi bàjẹ́ nítorí líle ọkàn rẹ, àní, tí ìwọ sì nkọjú ìjà sí ẹ̀mí-òtítọ́, pé kí ẹ̀mí rẹ lè parun. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ó sàn kí ẹ̀mí rẹ̀ kí ó parun, jù kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí ti ipasẹ̀ rẹ bọ́ sí ìparun, nípa ọ̀rọ̀ irọ́ àti ẹ̀tàn rẹ; nítorínã, bí ìwọ yíò bá tún sẹ́ẹ, kíyèsĩ, Ọlọ́run yíò kọlũ ọ́, tí ìwọ yíò sì yadi, tí ìwọ kò sì ní lè la ẹnu rẹ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó má lè tan àwọn ènìyàn yĩ mọ́. Nísisìyí, Kòríhọ̀ wí fún un pé: Èmi kò sẹ́ pé Ọlọ́run kan nbẹ, ṣùgbọ́n èmi kò gbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọ́run kan; èmi sì tún sọ pẹ̀lú, wípé ìwọ kò mọ̀ pé Ọlọ́run kan nbẹ; bí ìwọ kò bá sì lè fi àmì hàn mí, èmi kò ní gbàgbọ́. Nísisìyí Álmà wí fún un pé: Eleyĩ ni èmi yíò fi fún ọ fún àmì kan, pé ìwọ yíò yadi, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ mi; èmí sì sọ pé, ní orúkọ Ọlọ́run, ìwọ ó yadi, tí ìwọ kò sì ní lè fọhùn mọ́. Nísisìyí nígbàtí Álmà ti sọ àwọn ohun wọ̀nyí tán, Kòríhọ̀ yadi, tí kò si lè fọhùn mọ́, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Álmà. Àti nísisìyí, nígbàtí adájọ́ àgbà rí èyí, ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì kọọ́ sí Kòríhọ̀, pé: Njẹ́ ìwọ ha ti ní ìdánilójú nípa agbára Ọlọ́run? Ara tani ìwọ ha ti fẹ́ kí Álmà fiàmì rẹ̀ hàn? Ìwọ ha fẹ́ kí ó kọlũ ẹlòmíràn bí, láti fi àmì hàn ọ́? Kíyèsĩ, ó ti fi àmì hàn ọ́; àti nísisìyí ìwọ ó tún jìyàn síi báyĩ? Kòríhọ̀ sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì kọọ́ pé: Èmi mọ̀ pé mo ti yadi, nítorítí èmi kò lè fọhùn; èmi sì mọ̀ pé kò sí ohunkóhun bíkòṣe agbára Ọlọ́run ni ó lè mú eleyĩ dé bá mi; bẹ̃ni, èmi sì ti mọ̀ látẹ̀hìnwá pé Ọlọ́run kan nbẹ. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èṣù ni ó ti tàn mí; nítorítí ó farahàn mí ní ẹ̀yà ángẹ́lì, tí ó sì wí fún mi pé: Lọ gba àwọn ènìyàn yĩ padà, nítorítí nwọn ti ṣìnà nípa títẹ̀lé Ọlọ́run àìmọ̀ kan. Òun sì wí fún mi pé: Kò sí Ọlọ́run; bẹ̃ni, òun sì kọ́ mi ní ohun tí èmi yíò sọ. Èmi sì ti kọ́ni ní àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀; èmi sì ṣe ìkọ́ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nítorípé nwọ́n dùn mọ́ ọkàn ti ara; èmi sì nṣe ìkọ́ni wọn, àní títí èmi fi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣeyọrí, tó bẹ̃ tí èmi fi gbàgbọ́ dájúdájú pé òtítọ́ ni nwọ́n í ṣe; nítorí ìdí èyí ni èmi ṣe kọjú ìjà sí èyítí í ṣe òtítọ́, àní títí èmi fi mú ẹ̀gún nlá yĩ sí órí mi. Nísisìyí nígbàtí ó ti sọ eleyĩ, ó sì fi ẹ̀bẹ̀ rọ Álmà pé kí ó gbàdúrà sí Ọlọ́run kí ègún nã lè kúrò lórí òun. Ṣùgbọ́n Álmà wí fún un pé: Tí ègún yĩ bá kúrò lórí rẹ, ìwọ yíò tún darí ọkàn àwọn ènìyàn wọ̀nyí kúrò; nítorínã kí ó rí fún ọ àní gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ ti Olúwa. Ó sì ṣe tí a kò mú ègún nã kúrò lórí Kòríhọ̀; ṣùgbọ́n nwọ́n lé e jáde, ó sì nlọ kákiri láti ilé dé ilé, tí ó ntọrọ oúnjẹ jẹ. Nísisìyí, ní kété ni nwọ́n kéde ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Kòríhọ̀ jákè-jádò ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, adájọ́-àgbà ni ó fi ìkéde nã ránṣẹ́ sí gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ílẹ̀ nã, tí ó sì kéde sí àwọn tí nwọ́n ti gba ọ̀rọ̀ Kòríhọ̀ gbọ́ pé nwọ́n níláti ronúpìwàdà kankan, kí irú ìdájọ́ kannã má bã dé bá wọn. Ó sì ṣe ti gbogbo nwọn ní ìdánilójú nípa ìwà búburú Kòríhọ̀; nítorínã gbogbo nwọn yípadà sọ́dọ̀ Olúwa; èyí ni ó sì fi òpin sí àìṣedẽdé irú èyítí Kòríhọ̀ hù. Kòríhọ̀ sì nlọ kákiri láti ilé dé ilé, tí ó ntọrọ oúnjẹ fún ìrànlọ́wọ́ ara rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó kọjá lọ sí ãrin àwọn ènìyàn, bẹ̃ni, lãrín àwọn ènìyàn tí nwọ́n ti yapa kúrò lára àwọn ará Nífáì tí nwọ́n sì pe ara nwọn ní ará Sórámù, nítorípé ẹnì kan tí orúkọ rẹ̀ í ṣe Sórámù ni ó ndarí wọn—bí ó sì ti kọjá lọ sí ãrin wọn, kíyèsĩ, nwọn tẹ̃ mọ́lẹ̀, àní títí ó fi kú. Báyĩ ni a sì rẹ́hìn ẹni nã tí ó nyí ọ̀nà Olúwa po; báyĩ ni àwa sì ríi pé èṣù kò ni ti àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn ní ọjọ́ ìkẹhìn, ṣùgbọ́n òun yíò fà nwọ́n sínú ọ̀run àpãdì kankan. 31 Álmà síwájú iṣẹ́-ìránṣẹ́ kan láti lọ gba àwọn ará Sórámù tí nwọ́n ti ṣubú kúrò nínú òtítọ́—Àwọn ará Sórámù sẹ́ Krístì, nwọ́n gbàgbọ́ nínú ìmọ̀ èkè pé àṣàyàn ni nwọn íṣe, nwọ́n sì njọ́sìn ní ipa àwọn àdúrà tí nwọ́n ti gbékalẹ̀ ṣãjú—Áwọn oníṣẹ́ Ọlọ́run kún fún Ẹ̀mí Mímọ́—Àwọn ìpọ́njú nwọn di gbígbémì nínú ayọ̀ Krístì. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn ikú Kòríhọ̀, tí Álmà sì ti gbọ́ ìròhìn pé àwọnará Sórámù nyí ọ̀nà Olúwa po, àti pé Sórámù, ẹnití í ṣe olórí nwọn, ndarí ọkàn àwọn ènìyàn nã láti tẹríba fún àwọn ère tí kò lè sọ̀rọ̀, ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀sí kẹ́dùn nítorí ìwà àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã. Nítorítí ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ nlá fún Álmà láti mọ̀ nípa ìwà àìṣedẽdé tí ó wà lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀; nítorínã ọkàn rẹ̀ kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ìyapa àwọn ara Sórámù kúrò lára àwọn ará Nífáì. Nísisìyí, àwọn ará Sórámù ti kó ara nwọn jọ sí orí ilẹ̀ kan tí nwọn npè ní Ántíónọ́mù, èyítí ó wà ní ìhà ìwọ-oòrùn ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí ó wà nítòsí ãlà etí-òkun, tí ó wà ní apá gũsù ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, èyítí ó fẹ́rẹ́ bá aginjù tí ó wà ní ìhà gũsù pa ãlà, aginjù èyítí àwọn ará Lámánì kún inú rẹ̀. Nísisìyí, àwọn ará Nífáì bẹ̀rù púpọ̀ pé àwọn ará Sórámù yíò ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Lámánì, àti pé yíò jẹ́ ipa àdánù nlá fún àwọn ará Nífáì. Àti nísisìyí, bí ìwãsù ọ̀rọ̀ nã sì ṣe ní ipa nlá láti darí àwọn ènìyàn nã sí ipa ṣíṣe èyítí ó tọ́—bẹ̃ni, ó ti ní agbára tí ó tobi jùlọ lórí ọkàn àwọn ènìyàn nã ju idà tàbí ohun míràn tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí nwọn rí—nítorínã Álmà rọ́ pé ó jẹ́ ohun tí ó tọ̀nà pé kí àwọn kí ó lo agbára tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorínã ó mú Ámọ́nì, àti Áárọ́nì, àti Òmnérì; ó sì fi Hímnì sílẹ̀ ní ìjọ-onígbàgbọ́ ní Sarahẹ́múlà; ṣùgbọ́n àwọn mẹ́ta ìṣájú nnì ni ó mú pẹ̀lú rẹ̀, àti pẹ̀lú Ámúlẹ́kì àti Sísrọ́mù, tí nwọ́n wà ní Mẹ́lẹ́kì; ó sì mú méjì nínú àwọn ọmọkùrin rẹ̀ pẹ̀lú. Nísisìyí, èyítí ó dàgbàjù nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ni kò mú lọ pẹ̀lú rẹ̀, orúkọ rẹ̀ ni í sì í ṣe Hẹ́lámánì; ṣùgbọ́n orúkọ àwọn tí ó mú lọ pẹ̀lú rẹ̀ ni Ṣíblọ́nì àti Kọ̀ríántọ́nì; èyí sì ni orúkọ àwọn tí ó lọ pẹ̀lú rẹ̀ sãrin àwọn ará Sórámù, láti lọ wãsù ọ̀rọ̀ nã sí nwọn. Nísisìyí, àwọn ará Sórámù jẹ́ olùyapa-kúrò lára àwọn ará Nífáì; nítorínã, nwọ́n ti gbọ́ ìwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n nwọ́n ti ṣubú sínú àwọn àṣìṣe ńlá, nítorítí nwọn kò gbiyanju láti pa òfin Ọlọ́run mọ́, àti ìlànà rẹ̀, gẹ́gẹ́bí òfin Mósè. Bẹ̃ni nwọn kò sì kíyèsí ìṣe ìjọ-onígbàgbọ́, láti tẹ̀síwájú nínú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run lójojúmọ́, kí nwọ́n má bã bọ́ sínú ìdánwò. Bẹ̃ni, ní kúkúrú, nwọ́n yí ọ̀nà Olúwa po ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà; nítorínã, fún ìdí èyí, Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ sí orí ilẹ̀ nã láti lọ wãsù ọ̀rọ̀ nã sí nwọn. Nísisìyí, nígbàtí nwọ́n ti wá sínú ilẹ̀ nã, kíyèsĩ, sí ìyàlẹ́nu wọn ríi pé àwọn ará Sórámù ti kọ́ àwọn sínágọ́gù, tí nwọn sì máa kó ara nwọn nwọn, jọ ní ọjọ́ kan nínú ọ̀sẹ̀, èyítí nwọn npè ní ọjọ́ Olúwa; nwọ́n sì jọ́sìn ní ọ̀nà tí Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kò rí irú rẹ̀ rí; Nítorí nwọ́n ní ibi tí nwọ́n kọ́ ní ãrin sínágọ́gù nwọn, ibití Idìdedúró sí, èyítí ó ga tayọ orí; òkè orí èyítí kò gbà ju ẹyọ ẹnìkan lọ. Nítorínã, ẹnìkẹ́ni tí ó bá ní ìfẹ́ láti jọ́sìn níláti jáde lọ, kí ó si dúró lórí rẹ̀, kí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjẽjì sí òkè-ọ̀run, kí ó sì kígbe ní ohùn rara, wípé: Mímọ́ Ọlọ́run mímọ́; àwa gbàgbọ́ pé ìwọ ni Ọlọ́run, a sì gbàgbọ́ pé mímọ́ ni ìwọ í ṣe, àti pé ẹ̀mí ni ìwọ í ṣe ní ìgbà nnì, ẹ̀mí ni ìwọ sì í ṣe, àti pé ẹ̀mí ni ìwọ í ṣe títí láéláé. Ọlọ́run mímọ́, àwa gbàgbọ́ pé ìwọ tí ṣe ìpínyà wa kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wa; àwa kò sì gba àṣà àwọn arákùnrin wa gbọ́, èyítí àwọn bàbá nwọn gbé fún wọn nínú ìwà òmùgọ̀ wọn; ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé ìwọ ti yàn wá láti jẹ́ ọmọ mímọ́ rẹ; àti pẹ̀lú ìwọ ti sọọ́ di mímọ̀ fún wa pé kì yíò sí Krístì kankan. Ṣùgbọ́n ìwọ ni ọ̀kannã ní àná, ní òní, àti títí láé; ìwọ sì ti yàn wá kí àwa lè di ẹni-ìgbàlà, nígbàtí a yan àwọn tí ó yí wa ká láti lè bọ́ sínú ọ̀run àpãdì nípa ìbínú rẹ; nítorí ìwà mímọ́ wa yĩ, A! Ọlọ́run, a dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ; àwa sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti yàn wá, kí àwa má lè tẹ̀lé àwọn àṣà aṣiwèrè àwọn arákùnrin wa, èyítí ó ndè nwọ́n mọ́lẹ̀ sí ìgbàgbọ́ nínú Krístì, èyítí ó ndarí ọkàn nwọn láti ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, Ọlọ́run wa. Àwa sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, A! Ọlọ́run, pé àwa jẹ́ ẹnití a ti yàn àti àwọn ènìyàn mímọ́ Àmín. Báyĩ ni ó ṣe lẹ́hìn tí Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti gbọ́ àwọn àdúrà wọ̀nyí, ẹnu yà nwọ́n gidigidi rékọjá gbogbo ìwọ̀n. Nítorí kíyèsĩ, olúkúlùkù nwọn ni ó kọjá lọ láti gba irú àdúrà kannã. Nísisìyí nwọn npe orúkọ ibẹ̀ ní Rámiúpítọ́mù, èyítí ó túmọ̀ sí ibi-ìdúró mímọ́. Nísisìyí, lórí ibi-ìdúró yĩ, olúkúlùkù nwọn gbe ohùn àdúrà irú kannã sókè sí Ọlọ́run, tí nwọn sì ndúpẹ́ pé ó yàn nwọ́n, àti pé ó darí wọn kúrò ní ipa àṣà àwọn arákùnrin nwọn, àti pé nwọn kò rí wọn mú pẹ̀lú ẹ̀tàn láti gbàgbọ́ nínú àwọn ohun tí nbọ̀wá, èyítí nwọn kò mọ́ ohunkóhun nípa rẹ̀. Nísisìyí, lẹ́hìn tí àwọn ènìyàn nã bá ti gbé ohùn ọpẹ́ sókè tán lọ́nà yĩ, nwọn padà sí ilé wọn, ti nwọn kò sí ní sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run wọn mọ́ títí nwọn ó fi tún péjọpọ̀ sí ibi-ìdúró mímọ́ nã, láti gbé ohùn ọpẹ́ sókè lọ́nà yĩ. Nísisìyí nígbàtí Álmà rí eleyĩ, inú rẹ̀ bàjẹ́; nítorítí ó ríi pé ènìyàn búburú àti ẹni-ìlòdìsí ni nwọn íṣe; bẹ̃ni, ó rí i pé nwọn kó ọkàn wọn lé wúrà, àti lè fàdákà, àti lé onírurú ohun mèremère. Bẹ̃ni, ó sì ríi pẹ̀lú pé wọ́n nṣe ìgbéraga púpọ̀púpọ̀ nínú ọkàn nwọn. Ó sì gbé ohùn rẹ̀ sókè sí ọ̀run, ó sì kígbe, wípé: A! báwo ni yíò ti pẹ́ tó, A! Olúwa, ìwọ yíò ha jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ gbé ìsàlẹ̀ yĩ nínú ara, láti wo irú ìwà búburú nlá báyĩ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn? Kíyèsĩ, A! Ọlọ́run, nwọn nképè ọ́, ṣùgbọ́n ọkàn nwọn kún fún ìgbéraga. Kíyèsĩ, A! Ọlọ́run, nwọn nképè ọ́ pẹ̀lú ẹnu nwọn, ṣùgbọ́n ọkàn nwọn rú sókè sí ìgbéraga àní sí tílóbi, pẹle àwọn ohun asán ayé. Kíyèsĩ, A! Ọlọ́run mi àwọn aṣọ olówó-iyebíye wọn, àti àwọn òrùka-ọwọ́ wọn, àti ẹ̀gbà-ọwọ́ wọn, àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà wọn, àti ohun mèremère wọn gbogbo tí nwọ́n fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ ọ́; sì wọ́, ibití ọkàn wọn wà ni èyĩ, síbẹ̀ nwọ́n nképè ọ́ nwọn sì nwípé—Àwa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, A! Ọlọ́run, nítorípé ẹ̀yin ti ṣe wá ní ẹni-yíyàn níwájú nyin, nígbàtí àwọn míràn yíò ṣègbé. Bẹ̃ni, nwọ́n sì nsọ wípé ìwọ ti sọọ́ di mímọ̀ fún nwọn pé kò lè sí Krístì kankan. A! Olúwa Ọlọ́run, báwo ni yíò ti pẹ́ tó tí ìwọ yíò fi gbà kí irú ìwà búburú àti àìgbàgbọ́ bẹ̃ kí ó wà lãrín àwọn ènìyàn yĩ? A! Olúwa, ìwọ ìbá fún mi ní agbára, kí èmi lè faradà àwọn àìlera mi. Nítorítí aláìlera ni èmi íṣe, irú àwọn ìwà búburú lãrín àwọn ènìyàn yĩ sì jẹ́ ohun ẹ̀dùn fún ọkàn mi. A! Olúwa, ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀; ìwọ ìbá tu ọkàn mi nínú nípasẹ̀ Krístì. A! Olúwa, ìwọ ìbá gbà fún mi, kí èmi ní agbára láti lè jẹ́ kí èmi ó lè fi ìpamọ́ra gba àwọn ìpọ́njú wọ̀nyí tí yíò bá mi nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn yĩ. A! Olúwa, ìwọ ìbá tu ọkàn mi nínú, kí ó sì fún mi ní àṣeyọrí, àti àwọn alájọṣiṣẹ́pọ̀ mi tí nwọ́n wà pẹ̀lú mi—bẹ̃ni, Ámọ́nì, àti Áárọ́nì, àti Òmnérì, àti Ámúlẹ́kì, àti Sísrọ́mù, àti àwọn ọmọ mi méjẽjì pẹ̀lú—bẹ̃ni, àní ìwọ ìbá tu gbogbo àwọn wọ̀nyí nínú, A! Olúwa. Bẹ̃ni, ìwọ ìbá tu ọkàn wọn nínú nípasẹ̀ Krístì. Ìwọ ìbá fi fún nwọn, kí nwọn lè lágbára, kí nwọn lè faradà ìpọ́njú tí yíò bá nwọn nítorí ìwà àìṣedẽdé àwọn ènìyàn yĩ. A! Olúwa, ìwọ ìbá fi fún wa kí àwa lè ní àṣeyọrí láti lè mú wọn wá sọ́dọ̀ rẹ nípasẹ̀ Krístì. Kíyèsĩ, A! Olúwa, ẹ̀mí nwọn níyelórí, arákùnrin wa sì ni púpọ̀ nínú nwọn íṣe; nítorínã, fún wa, A! Olúwa, ní agbára àti ọgbọ́n tí àwa yíò fi tún mú àwọn wọ̀nyí, àwọn arákùnrin wa, wá sọ́dọ̀ rẹ. Nísisìyí, ó sì ṣe nígbàtí Álmà ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Sì wò ó, bí ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí nwọn, nwọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Lẹ́hìn èyí, nwọ́n sì pínyà kúrò lọ́dọ̀ ara nwọn, láìṣe àníyàn nípa ohun tí nwọn yíò jẹ, tabí tí nwọn yíò mu, tàbí tí nwọn yíò fi bora. Olúwa sì pèsè fún nwọn tí ebi kò pa nwọ́n, bẹ̃ sì ni òrùngbẹ kò gbẹ nwọ́n; bẹ̃ni, ó sì tún fún nwọn lágbára láti má rí ìpọ́njú kankan, àfi kí nwọn gbé nwọn mì nínú ayọ̀ Krístì. Nísisìyí èyí sì wà ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà Álmà; ó sì rí bẹ̃ nítorípé ó gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́. 32 Álmà nkọ́ àwọn tálákà ènìyàn tí ìpọ́njú nwọn ti rẹ̀ wọn sílẹ̀—Ìgbàgbọ́ jẹ́ ìrètí nínú ohun èyítí a kò rí tĩ ṣe òtítọ́—Álmà jẹ́rĩ pé àwọn ángẹ́lì a máa jíṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé—Álmà f i ọ̀rọ̀ nã wé irúgbìn—A níláti gbìn ín kí a sì bọ́ ọ—Yíò sì dàgbà di igi lara eyití a ó ká èso ìyè àìnípẹ̀kun. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Ósì ṣe tí nwọ́n jáde lọ, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n sì nwọ inú àwọn sínágọ́gù nwọn, àti inú ilé nwọn; bẹ̃ni, nwọn sì nwãsù ọ̀rọ̀ nã nínú àwọn ìgboro nwọn. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí nwọ́n ti ṣe lãlã púpọ̀ lãrín wọn, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ní àṣeyọrí lãrín àwọn tálákà ènìyàn nwọn; nítorí kíyèsĩ, nwọ́n lé nwọn jáde kúrò nínú àwọn sínágọ́gù wọn nítorí aṣọ nwọn tí kò níyelórí— Nítorínã, nwọn kò jẹ́ kí nwọn wọ inú àwọn sínágọ́gù nwọn láti sin Ọlọ́run, nítorítí wọ́n kà nwọ́n sí ẹni-elẽrí; nítorínã nwọ́n jẹ́ tálákà; àní, àwọn arákùnrin wọn kà nwọ́n sí ìdàrọ́; nítorínã nwọ́n jẹ́ tálákà nípa àwọn ohun ti ayé; nwọ́n sì jẹ́ oníròbìnújẹ́ ọkàn ènìyàn. Nísisìyí, bí Álmà ti nkọ́ni tí ó sì nbá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀ lórí òkè Onídà, ọ̀pọ̀ ènìyàn tọ̣́ wá, tí nwọn íṣe àwọn tí a ti nsọ nípa wọn ṣãjú, tí nwọn íṣe oníròbìnújẹ́ ọkàn ènìyàn, nítorípé nwọ́n jẹ́ aláìní nípa àwọn ohun ti ayé. Nwọ́n sì tọ Álmà wá; ẹnìkan nínú nwọn èyítí íṣe aṣãjú nwọn sì wí fún un pé: Wọ́, kíni kí àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí ó ṣe, nítorítí gbogbo ènìyàn a máa kẹ́gàn wọn nítorí àìní wọn, bẹ̃ ni, pãpã àwọn àlùfã wa; nítorítí nwọ́n sì ti lé wa jáde kúrò nínú sínágọ́gù wa, tí àwa ti ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti kọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ara wa; nwọ́n sì ti lé wa jáde nítorí ipò àìní wa èyítí ó tayọ; àwa kò sì ní ibi tí àwa yíò ti máa sin Ọlọ́run wa; sì wọ́, kíni àwa yíò ṣe? Àti nísisìyí nígbàtí Álmà gbọ́ eleyĩ, ó yí ojú rẹ̀ sọ́dọ̀ nwọn, ó sì dojúkọ ọ́, ó sì ṣe àkíyèsí pẹ̀lú ayọ̀ nlá; nítorítí ó kíyèsĩ pé ìpọ́njú nwọn ti rẹ̀ nwọ́n sílẹ̀ nítọ́tọ́, tí nwọ́n sì wà ní ipò ìṣetán láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nã. Nítorínã, kò bá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀ mọ́; ṣùgbọ́n ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì kígbe sí àwọn tí ó nwò, tí nwọ́n sì ti ronúpìwàdà nítọ́tọ́, ó sì wí fún nwọn pé: Èmi ṣe àkíyèsí pé onírẹ̀lẹ̀ọkàn ni ẹ̀yin íṣe; bí ó bá sì rí bẹ̃ alábùkún-fún ni ẹ̀yin íṣe. Ẹ kíyèsĩ, arákùnrin nyín ti wípé, kíni àwa yíò ṣe?—nítorítí nwọ́n lé wa jáde kúrò nínú àwọn sínágọ́gù wa, tí àwa kò sì lè sin Ọlọ́run wa. Ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín, ẹ̀yin ha lérò pé ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run nyín bíkòṣe nínú àwọn sínágọ́gù nyín nìkan? Ju gbogbo èyĩ, èmi yíò bẽrè, ẹ̀yin ha lérò pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ sin Ọlọ́run àfi ni ẹ̃kan ṣoṣo ní ọ́sẹ̀ bi? Èmi wí fún nyín, ó dára tí nwọ́n lée nyín jáde kúrò nínú àwọn sínágọ́gù nyín, kí ẹ̀yin kí ó lè rẹ ara nyín sílẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó sì kọ́ ọgbọ́n, nítorípé ó jẹ́ ohun tí ó yẹ pé kí ẹ̀yin kọ́ ọgbọ́n; nítorítí a lée nyín jáde, tí àwọn arákùnrin nyín sì nkẹ́gàn nyín nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìní nyín, ni ẹ̀yin ṣe rẹ ọkàn nyín sílẹ̀; nítorí àwọn ohun wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe rẹ ara nyín sílẹ̀. Àti nísisìyí, nítorítí a ti fi ipá mú nyín rẹ ara nyín sílẹ̀, alábùkún-fún ni ẹ̀yin íṣe; nítorítíènìyàn, nígbàmíràn, tí a bá fi ipá múu láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, yíò wá ìrònúpìwàdà; àti nísisìyí dájúdájú, ẹnìkẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà yíò rí ãnú; ẹnití ó bá sì rí ãnú, tí ó sì forítĩ dé òpin, òun nã ni a ó gbàlà. Àti nísisìyí, gẹ́gẹ́bí mo ti wí fún nyín, pé nítorítí a ti fi ipá múu nyín láti rẹ ara nyín sílẹ̀, tí ẹ̀yin di alábùkún-fún, njẹ́ ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé àwọn ẹnití ó bá rẹ ara nwọn sílẹ̀ nítọ́tọ́ nítorí ọ̀rọ̀ nã jẹ́ alábùkún-fún jùlọ? Bẹ̃ni, ẹnití ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítọ́tọ́, tí ó sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì forítì í dé òpin, òun nã ni a ó bùkún fún—bẹ̃ni, tí a ó bùkún fún un jù àwọn tí a fi ipá mú láti rẹ ara nwọn sílẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìní nwọn. Nítorínã, alábùkún-fún ni àwọn tí nwọ́n rẹ ara nwọn sílẹ̀ láìjẹ́ wípé a fi ipá mú nwọn láti rẹ ara nwọn sílẹ̀; tàbí kí a wípé, ni ọ̀nà míràn, alábùkún-fún ni ẹni nã tí ó gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́, tí a sì rìí bọmi láì ṣe oríkunkun, bẹ̃ni, láìmọ ọ̀rọ̀ nã, tàbí pé láìfi ipá mú u láti mọ̀, kí wọn tó lè gbàgbọ́. Bẹ̃ni, nwọ́n pọ̀ tí nwọn a máa wípé: Bí ìwọ bá lè fi àmì hàn fún wa láti ọ̀run wá, nígbànã ni àwa yíò mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú; nígbànã ní àwa yíò sì gbàgbọ́. Nísisìyí mo bẽrè, njẹ́ ìgbàgbọ́ ni èyí íṣe? Ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín, rárá; nítorípé bí ènìyàn bá mọ́ ohun kan kò sí ìdí fún un láti gbà á gbọ́, nítorítí ó ti mọ̣́. Àti nísisìyí, báwo ni ègún orí ẹni nã yíò ha ti pọ̀ tó, tí ó mọ́ ìfẹ́-inú Ọlọ́run, tí kò sì ṣeé, ju ti ẹnití ó gbàgbọ́ nìkan, tàbí tí ó ní ìdí láti gbàgbọ́, tí ó sì ṣubú sí inú ìwàìrékọjá? Nísisìyí, nínú eleyĩ ni kí ẹ ti ṣe ìdájọ́. Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún nyín, pé bákannã ni ó rí ní ìhà kan àti èkejì; yíò sì rí fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Àti nísisìyí, bí èmi ti sọ nípa ti ìgbàgbọ́—ìgbàgbọ́ kĩ ṣe kí ènìyàn ní ìmọ̀ pípé nípa ohun gbogbo; nítorínã, bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́, ẹ̀yin ní ìrètí fún àwọn ohun tí a kò rí, èyítí íṣe òtítọ́. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín, èmi sì fẹ́ kí ẹ rántí, pé Ọlọ́run nṣãnú fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá gba orúkọ rẹ̀ gbọ́; nítorínã ó fẹ́, lọ́nà àkọ́kọ́, pé kí ẹ̀yin gbàgbọ́, bẹ̃ni, àní nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àti nísisìyí, ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ènìyàn nípasẹ̀ àwọn ángẹ́lì, bẹ̃ni, kĩ ṣe àwọn ọkùnrin nìkan, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin nã pẹ̀lú. Nísisìyí, èyí kĩ ṣe gbogbo rẹ̀; àwọn ọmọdé nã ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run a máa fún nwọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, èyítí a máa da àwọn ọlọgbọ́n àti àwọn amòye lãmú. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, bí ẹ̀yin ṣe fẹ́ kí èmi kí ó sọ fún nyín ohun tí ẹ̀yin ó ṣe nítorípé nwọ́n npọ́n nyín lójú tí nwọ́n sì lée nyín jáde—nísisìyí èmi kò fẹ́ kí ẹ rò pé èmi fẹ́ láti dáa nyín lẹ́jọ́ àfi gẹ́gẹ́bí èyítí í ṣe òtítọ́— Nítorípé èmi kò lérò pé gbogbo nyín ni a ti fi ipá mú láti rẹ ara nyín sílẹ̀; nítorítí èmi gbàgbọ́ pé àwọn kan wà lãrín nyín tí nwọn ò rẹ ara nwọn sílẹ̀, jẹ́ kí nwọ́n wà ní ipòkípò tí nwọn ìbá wà. Nísisìyí, bí èmi ti sọ nípa ìgbàgbọ́—pé kĩ ṣe ìmọ̀ pípé—bẹ̃ nã ni ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí rí. Ẹ̀yin kò lè mọ̀ nípa ìdánilójú nwọn nígbà àkọ́kọ́, ní kíkún, jù pé ìgbàgbọ́ jẹ́ ìmọ̀ pípé. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin bá lè jí kí ẹ̀yin sì ta ọkàn nyín jí, àní sí àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ̀yin sì ní ìgbàgbọ́ kékeré, bẹ̃ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé kí ẹ̀yin má ṣe jù pé kí ẹ ní ìfẹ́ láti gbàgbọ́, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yĩ ṣiṣẹ́ nínú nyín, àní títí ẹ̀yin yíò gbàgbọ́ ní ọ̀nà tí ẹ̀yin yíò gba ohun tí ẹ̀mí nsọ. Nísisìyí, àwa yíò fi ọ̀rọ̀ nã wé irúgbìn. Nísisìyí, tí ẹ̀yin bá gba ohun tí èmi nsọ, pé kí a gbin irúgbìn nã sínú ọkàn nyín, ẹ wọ́, bí ó bá ṣe irúgbìn òtítọ́, tàbí irúgbìn rere, tí ẹ̀yin kò bá fã tu nípa àìgbàgbọ́ nyín, kí ẹ̀yin tako Ẹ̀mí Olúwa, ẹ kíyèsĩ, yíò bẹ̀rẹ̀sí wú nínú ọkàn nyín; bí ẹ̀yin bá sì ní irú àpẹrẹ ọkàn wíwú báyĩ, ẹ̀yin yíò bẹ̀rẹ̀sí sọ nínú ara nyín pé ó níláti jẹ́ pé—ó di dandan ki eyi jẹ irúgbìn rere, tàbí pé rere ni ọ̀rọ̀ nã í ṣe, nítorítí ó bẹ̀rẹ̀sí mú ìdàgbàsókè bá ẹ̀mí mi; bẹ̃ni, ó bẹ̀rẹ̀sí tan ìmọ́lẹ̀ sí òye mi, bẹ̃ni, ó bẹ̀rẹ̀sí fún mi ní ayọ̀. Nísisìyí ẹ kíyèsí i, njẹ́ eleyĩ kò ha ní mú ìgbàgbọ́ nyín tóbi síi bí? Mo wí fún nyín, bẹ̃ni; bíótilẹ̀ríbẹ̃, kòì tĩ dàgbà dé ibi ìmọ̀ pípé. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, bí irúgbìn nã ṣe nwú síi, tí ó sì hù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà, ẹ̀yin nã níláti sọ wípé irúgbìn nã dára; nítorítí, ẹ kíyèsĩ pé ó wú, ó sì hù, ó sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà. Àti nísisìyí, ẹ wọ́, èyĩ kò ha ní mú kí ìgbàgbọ́ nyín dàgbà síi bí? Bẹ̃ni, yíò mú ìgbàgbọ́ nyín dàgbà síi: Nítorítí ẹ̀yin yíò wípé mo mọ̀ pé irúgbìn dáradára ni èyí íṣe; nítorítí ẹ kíyèsĩ ó hù ó sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, njẹ́ ó dá nyín lójú pé irúgbìn dáradára ni èyĩ ṣe? Èmi wí fún un yín, bẹ̃ni; nítorípé irúgbìn dáradára yíò mú èso irú ara rẹ̀ jáde wá. Nítorínã, bí irúgbìn bá dàgbà, dáradára ni íṣe, ṣùgbọ́n bí kò bá dàgbà, ẹ kíyèsĩ, kĩ ṣe dáradára, nítorínã a ó mú u kúrò. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, nítorípé ẹ̀yin ti ṣe ìdánwò nnì, tí ẹ ti gbin irúgbìn nã, tí ó sì wú, tí ó sì hù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà, ẹ̀yin níláti mọ̀ pé irúgbìn nã dára. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, njẹ́ ìmọ̀ nyín ha pé bí? Bẹ̃ni, ìmọ̀ nyín pé nínú ohun nã, ìgbàgbọ́ nyín sì wà láìlò; èyí rí bẹ̃ nítorípé ẹ mọ̀, nítorítí ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀rọ̀ nã ti wú ọkàn nyín sókè, ẹ̀yin sì tún mọ̀ pé ó ti hù, pé ìmọ́lẹ̀ sì ti ntàn sí òye nyín, ìmọ̀ ọkàn nyín sì ti bẹ̀rẹ̀sí pọ̀ síi. A! njẹ́ báyĩ, èyí kò ha jẹ́ òdodo? Èmi wí fún nyín, bẹ̃ni, nítorípé ìmọ́lẹ̀ ni íṣe; ohunkóhun tĩ bá sĩ ṣe ìmọ́lẹ̀, ó jẹ́ èyítí ó dára, nítorípé a mọ́ ìyàtọ̀ rẹ̀ lãrín àwọn yọ́kù, nítorínã, ẹ̀yin níláti mọ̀ pé ó dára; àti nísisìyí kíyèsĩ, lẹ́hìn tí ẹ̀yin ti tọ́ ìmọ́lẹ̀ yí wò, njẹ́ ìmọ̀ nyín pé bí? Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún nyín, Rárá; ẹ̀yin kò sì gbọ́dọ̀ pa ìgbàgbọ́ nyín tì, nítorípé ẹ̀yin ti lo ìgbàgbọ́ nyín láti gbin irúgbìn nã, kí ẹ̀yin kí ó lè sapá nínú ìdanwò nnì láti ríi bóyá dáradára ni irúgbìn nã í ṣe. Sì kíyèsĩ, bí igi nã ṣe ndàgbà, ẹ̀yin yíò wípé: Ẹ jẹ́ kí a tọ́ọ dàgbà dáradára, kí ó lè ta gbòngbò, kí ó lè dàgbà, kí ó sì so èso fún wa. Àti nísisìyí i, ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin bá tọ́ ọ dáradára, yíò ta gbòngbò, yíò sì dàgbà, yíò sì so èso jáde wá. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá pa igi nã tì, tí ẹ kò sì bìkítà fún bíbọ́ rẹ̀, ẹ kíyèsĩ kì yíò ní gbòngbò kankan; nígbàtí ìgbóná oòrùn bá sì dé tí ó sì jó o, nítorípé kò ní gbòngbò, yíò rẹ̀ dànù ẹ̀yin ó sì fã tu sọnù. Nísisìyí, eleyĩ kò rí bẹ̃ nítorípé irúgbìn nã kò dára, tàbí nítorípé èso rẹ̀ kò dára; ṣùgbọ́n ó rí bẹ̃ nítorípé ilẹ̀ nyín ti ṣá, ẹ̀yin kò sì tọ́ igi nã dàgbà, nítorínã, ẹ̀yin kò lè rí èso rẹ̀ gbà. Bákannã ni ó rí tí ẹ̀yin kò bá tọ́ ọ̀rọ̀ nã dàgbà, tí ẹ̀yin sì fojúsọ́nà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ sí èso rẹ̀, ẹ̀yin kò lè ká èso igi ìyè láéláé. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin yíò bá tọ́ ọ̀rọ̀ nã dàgbà, àní, bọ́ igi nã nígbàtí ó bẹ̀rẹ̀sí dàgbà, nípa ìgbàgbọ́ nyín pẹ̀lú ìtẹramọ́ nlá, àti ìpamọ́ra pẹ̀lú, tí ẹ̀yin sì fojúsọ́nà sí èso rẹ̀, yíò ta gbòngbò; ẹ sì kíyèsí, yíò sì jẹ́ igi tí yíò máa sun sí ìyè àìnípẹ̀kun. Àti nítorí ìtẹramọ́ nyín àti ìgbàgbọ́ nyín, àti ìpamọ́ra nyín tí ẹ̀yin fi tọ́ ọ̀rọ̀ nã, pé kí ó lè ta gbòngbò nínú nyín, ẹ kíyèsĩ, láìpẹ́ ọjọ́, ẹ̀yin yíò ká èso rẹ̀, èyítí ó jẹ́ iyebíye jùlọ, èyítí ó dùn tayọ gbogbo ohun tí ó dùn, èyítí ó sì funfun tayọ gbogbo ohun tí ó funfun, bẹ̃ni, tí ó sì mọ́ tayọ gbogbo ohun tí ó mọ́; ẹ̀yin yíò sì máa jẹ èso yĩ àní títí ẹ̀yin yíò fi yó, tí ebi kò ní pa nyín, bẹ̃ sì ni òùngbẹ kò ní gbẹ nyín. Nígbànã, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀yin yíò kórè èrè ìgbàgbọ́ nyín, àti ìtẹramọ́ nyín, àti ìpamọ́ra, àti ìfaradà, bí ẹ̀yin ṣe dúró de ìgbàtí igi nã yíò so èso jáde wá fún nyín. 33 Sénọ́sì kọ́ni pé kí ènìyàn ó máa gbàdúrà kí nwọ́n sì máa jọ́sìn ní ibi gbogbo, àti pé a mú ìdánilẹ́bi kúrò nítorí Ọmọ nã—Sénọ́kì kọ́ni pé ènìyàn nrí ãnú gbà nítorí Ọmọ nã—Mósè ti gbé irú ẹ̀yà Ọmọ Ọlọ́run sókè nínú aginjù. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí, lẹ́hìn tí Álmà ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, nwọ́n ránṣẹ́ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti mọ̀ bóyá kí àwọn gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kanṣoṣo, pé kí nwọn lè rí èso nã gbà èyítí ó ti sọ nípa rẹ̀, tàbí bí nwọn ó ṣe gbin irúgbìn nã, tàbí ọ̀rọ̀ nã èyítí ó ti sọ nípa rẹ̀, tí ó ní a níláti gbìn sínú ọkàn nwọn; tàbí báwo ni kí nwọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀sí lò ìgbàgbọ́ nwọn. Álmà sì wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti sọ wípé ẹ kò lè sin Ọlọ́run nyín nítorípé nwọ́n lée nyín jáde kúrò nínú sínágọ́gù nyin. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín, bí ẹ̀yin bá rò pé ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run, ẹ̀yin ṣìnà gidigidi, ó sì yẹ kí ẹ̀yin wá inú ìwé-mímọ́; bí ẹ̀yin bá rò pé nwọ́n ti kọ́ọ nyín ní ohun yĩ, nwọn kò yée nyín. Njẹ́ ẹ̀yin ha rántí pé ẹ ti kà nípa ohun tí Sénọ́sì, wòlĩ ìgbà nnì, ti sọ nípa àdúrà àti ìjọ́sìn bí? Nítorítí ó wípé: Alãnú ni ìwọ íṣe, A! Ọlọ́run, nítorítí ìwọ ti gbọ́ àdúrà mi, àní nígbàtí mowà nínú aginjù; bẹ̃ni, ìwọ ṣãnú nígbàtí mo gbàdúrà nípa àwọn tí nwọn jẹ́ ọ̀tá mi, ìwọ sì mú nwọn yọ́nú sí mi. Bẹ̃ni, A! Ọlọ́run, ìwọ sì ṣãnú fún mi nígbàtí mo ké pè ọ́ nínú pápá mi; nígbàtí èmi ké pè ọ́ nínú àdúrà mi, ìwọ sì gbọ́ mi. Àti pẹ̀lú, A! Ọlọ́run, nígbàtí èmi lọ sínú ilé mi, ìwọ gbọ́ mi nínú àdúrà mi. Nígbàtí èmi sì wọ inú ìyẹ̀wù mi lọ, A! Olúwa, tí mo sì gbàdúrà sí ọ, ìwọ gbọ́ mi. Bẹ̃ni, ìwọ a máa ṣãnú fún àwọn ọmọ rẹ nígbàtí nwọ́n bá ké pè ọ́, kí ìwọ kí ó lè gbọ́ nwọn láìṣe ènìyàn, ìwọ yíò sì gbọ́ nwọn. Bẹ̃ni, A! Ọlọ́run, ìwọ ti ṣãnú fún mi, ó sì ti gbọ́ igbe mi ní àwùjọ àwọn ènìyàn rẹ. Bẹ̃ni, ìwọ sì ti gbọ́ mi pẹ̀lú nígbàtí nwọ́n lé mi jáde, tí àwọn ọ̀tá mi sì fi mí ṣẹ̀sín; bẹ̃ni, ìwọ gbọ́ igbe mi, o sì bínú sí àwọn ọ̀tá mi, ìwọ sì bẹ̀ nwọ́n wò nínú ìbínú rẹ pẹ̀lú ìparun kánkán. Ìwọ sì gbọ́ mi nítorí ìpọ́njú mi àti òdodo mi; nítorí Ọmọ rẹ ni ìwọ sì ṣe ti ṣãnú fún mi báyĩ, nítorínã èmi yíò ké pè ọ́ nínú ìpọ́njú mi, nítorípé nínú rẹ ni ayọ̀ mi wà; nítorítí ìwọ ti mú ìdájọ́ rẹ kúrò lórí mi, nítorí ti Ọmọ rẹ. Àti nísisìyí Álmà sì wí fún nwọn pé: Njẹ́ ẹ̀yin ha gba àwọn ìwé-mímọ́ tí àwọn ará ìgbà nnì kọ gbọ́ bí? Ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin bá gbà nwọ́n gbọ́, ẹ ó gba ohun tí Sénọ́sì sọ gbọ́; nítorí, ẹ kíyèsĩ ó wípé: Ìwọ ti mú ìdájọ́ rẹ kúrò nítorí Ọmọ rẹ. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi yíò bẽrè bí ẹ̀yin bá ti ka àwọn ìwé-mímọ́? Bí ẹ̀yin bá ti kà nwọ́n, báwo ni ẹ̀yin ṣe lè ṣe aláìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run? Nítorítí a kò kọọ́ pé Sénọ́sì nìkan ni ó sọ nípa ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n Sénọ́kì nã sọ nípa àwọn ohun wọ̀nyí— Nítorí, ẹ kíyèsĩ, ó wípé: Ìwọ nbínú, A! Olúwa, sí àwọn ènìyàn yĩ, nítorípé nwọn kò ní òye nípa ãnú rẹ tí ìwọ ti fi fún nwọn nítorí ti Ọmọ rẹ. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀yin ríi pé wòlĩ kejì ìgbà nnì ti ṣe ìjẹ́rĩ sí nípa Ọmọ Ọlọ́run, àti nítorípé àwọn ènìyàn nã kọ̀ láti ní òye ọ̀rọ̀ rẹ̀ nwọ́n sọọ́ ní òkúta pa. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èyĩ nìkan kọ́; àwọn wọ̀nyí nìkan kọ́ ni ó ti sọ̀rọ̀ nípa Ọmọ Ọlọ́run. Ẹ kíyèsĩ, Mósè sọ nípa rẹ̀; bẹ̃ni, kí ẹ sì wọ́, a gbé irú rẹ̀ sókè nínú aginjù, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá gbé ojú sókè wò ó yíò yè. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó sì wò ó tí nwọn sì yè. Ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn tí ohun wọ̀nyí yé, èyí, nítorí líle ọkàn nwọn. Ṣùgbọ́n púpọ̀ ni àwọn tí ọkàn nwọn le tó bẹ̃ tí nwọn kò wọ́, nítorínã, nwọ́n parun. Báyĩ, ìdí rẹ̀ tí wọn kò fi ní wò ó ni wípé nwọn kò gbàgbọ́ pé yíò wò nwọ́n sàn. A! ẹ̀yin ará mi, bí ẹ̀yin bá lè rí ìwòsàn nípa fífi ojú nyín wò ṣá kí ẹ̀yin lè rí ìwòsàn, njẹ́ ẹ̀yin kò ní wọ́ ní kíákíá, tàbí ó tẹ́ẹ nyín lọ́rùn láti sé ọkàn nyín le nínú àìgbàgbọ́, kí ẹ sì ya ọ̀lẹ, kí ẹ sì má lè fi ojú nyín wọ́, tí ẹ̀yin ó sì parun? Bí ó bá rí bẹ̃, ègbé yíò wá sí orí nyín; ṣùgbọ́n bí kò bá rí bẹ̃, ẹ fi ojú nyín wọ́ nígbànã, kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀sí gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, pé ó nbọ̀wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ padà, àti pé yíò jìyà yíò sì kú fún ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nwọn; àti pé yíò tún jínde kúrò nínú ipò òkú, èyítí yíò mú àjĩnde-òkú nã ṣẹ, tí gbogbo ènìyàn yíò dúró níwájú rẹ̀, fún ìdájọ́, gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ ọwọ́ nwọn, ní ọjọ́ ìkẹhìn nnì tí í ṣe ọjọ́ ìdájọ́. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi fẹ́ kí ẹ gbin ọ̀rọ̀ yĩ sínú ọkàn nyín, bí ó sì ṣe bẹ̀rẹ̀sí wú sókè, bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ̀yin bọ́ọ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nyín. Ẹ sì kíyèsĩ, yíò di igi, tí yíò sì máa sun sí ìyè àìlópin nínú nyín. Kí Ọlọ́run kí ó sì jẹ́ kí ìnira nyín di fífúyẹ́, nípasẹ̀ ayọ̀ nínú Ọmọ rẹ̀. Gbogbo nkan wọ̀nyí ni ẹ̀yin lè ṣe, bí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ àti ṣeé. Àmín. 34 Ámúlẹ́kì ṣe ìjẹ́rìsí pé ọ̀rọ̀ nã wà nínú Krístì sí ìgbàlà—Àfi bí a bá ṣe ètùtù, gbogbo ènìyàn ni yíò ṣègbé. Gbogbo òfin Mósè ni ó tọ́ka sí ìfirúbọ Ọmọ Ọlọ́run—Ìlànà ìràpadà ti ayérayé dúró lórí ìgbàgbọ́ àti ìrònúpìwàdà—Ẹ máa gbàdúrà fún ìbùkún lórí ohun ara àti ti ẹ̀mí—Ayé yĩ ni àkokò fún ènìyàn láti múrasílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run—Ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà nyín pẹ̀lú ìbẹ̀rù níwájú Ọlọ́run. Ní ìwọ ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe, nígbàtí Álmà ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún nwọn, ó jókọ́ lélẹ, Ámúlẹ́kì sì dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀sí kọ́ nwọn ní ẹ̀kọ́, ó wípé: Ẹ̀yin arákùnrin mi, mo lérò pé ó ṣòro pé kí ẹ̀yin ó wà nínú àìmọ̀ ní ti àwọn ohun tí a ti sọ nípa bíbọ̀ Krístì, ẹnití a ṣe ìkọ́nilẹ̃kọ́ nípa rẹ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run nií ṣe; bẹ̃ni, èmi mọ̀ pé nwọ́n ti ṣe ìkọ́ni-lẹ́kọ̣́ àwọn nkan wọ̀nyí fún nyín lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ẹ̀yin tó yapa kúrò lọ́dọ̀ wa. Àti bi ẹ̀yin ṣe fẹ́ kí arákùnrin mi àyànfẹ́ jẹ́ kí ẹ mọ́ ohun tí ẹ̀yin níláti ṣe, nítorí ìpọ́njú nyín; òun sì ti bá nyín sọ̀rọ̀ díẹ̀ láti múra ọkàn nyín sílẹ̀; bẹ̃ni, òun sì ti gbà nyín níyànjú pé kí ẹ ní ìgbàgbọ́ àti sũrù— Bẹ̃ni, àní pé kí ẹ̀yin kí ó ní ìgbàgbọ́ púpọ̀ tí ẹ ó fi gbin ọ̀rọ̀ nã sínú ọkàn nyín, kí ẹ̀yin fi lè ṣe àgbéyẹ̀wò dídára rẹ̀. Àwa sì ti rí i pé ìbẽrè pàtàkì tí ó wà nínú ọkàn nyín ni pé bóyá ọ̀rọ̀ nã jẹ́ ti Ọmọ Ọlọ́run, tàbí bóyá kò ní sí Krístì kankan. Ẹ̀yin sì tún ríi pé arákùnrin mi ti fií hàn nyín, ní ọ̀nà tí ó pọ̀, pé ọ̀rọ̀ nã wà nínú Krístì sí ìgbàlà. Arákùnrin mi ti sọ nípa àwọn ọ̀rọ̀ Sénọ́sì, pé ìràpadà a máa wá nípasẹ̀ Ọmọ Ọlọ́run, àti pẹ̀lú, ó ti sọ nípa àwọn ọ̀rọ̀ Sénọ́kì; òun sì tún ti fi ọ̀rọ̀ lọ Mósè, láti fihàn pé òtítọ́ ni àwọn ohun wọ̀nyí íṣe. Àti nísisìyí, kíyèsĩ èmi yíò jẹ́rĩ fúnrami pé òtítọ́ ni àwọn ohun wọ̀nyí íṣe. Ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín pé èmi mọ̀ pé Krístì nbọ̀wá sí ãrin àwọn ọmọ ènìyàn, láti gbé gbogbo ìwàìrékọjá àwọn ènìyàn rẹ̀ wọ ara rẹ̀, àti pé òun yíò sì jẹ́ ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀àgbáyé; nítorítí Olúwa Ọlọ́run ni ó ti wí i. Nítorítí ó jẹ́ ohun tí ó tọ̀nà pé kí ẹnìkan ó ṣe ètùtù; nítorí gẹ́gẹ́bí ìlànà nlá ti Ọlọ́run Ayérayé ètùtù gbọ́dọ̀ jẹ́ ṣíṣe, bíkòjẹ́ bẹ̃ gbogbo ènìyàn yíò ṣègbé; bẹ̃ni, ọlọ́ríkunkun ni gbogbo nwọn í ṣe; bẹ̃ni, gbogbo nwọn ti ṣubú, nwọ́n sì ti sọnù, nwọn ó sì ṣègbé àfi nípasẹ̀ ètùtù nã èyítí ó tọ̀nà ní ṣíṣe. Nítorítí ó tọ̀nà pé kí ìrúbọ nlá kan tĩ ṣe àṣekẹ́hìn kí ó wà; bẹ̃ni, kĩ ṣe ìrúbọ tí a fi ènìyàn ṣe, tàbí ti ẹranko, tàbí ti ẹyẹkẹ́yẹ; nítorítí ko le jẹ́ ìrúbọ tí ènìyàn ṣe; ṣùgbọ́n ó níláti jẹ́ ìrúbọ tí íṣe èyí tí kò ní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin àti ti ayérayé. Nísisìyí kò sí ẹnìkẹ́ni tí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ rúbọ tí yíò sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn. Nísisìyí, bí ẹnìkan bá pànìyàn, ẹ kíyèsĩ, njẹ́ òfin wa, èyítí ó tọ́, yíò ha gba ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀ bí? Èmi wí fún nyín, Rárá. Ṣùgbọ́n òfin ni pé kí a gba ẹ̀mí ẹnití ó pànìyàn; nítorínã kò sí ohun nã lẹ́hìn ètùtù èyítí kò ní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin nnì tí ó lè ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. Nítorínã, ó tọ̀nà pé kí ìrúbọ nlá kan tĩ ṣe àṣekẹ́hìn kí ó wà, lẹ́hìn nã sì ni ìtàjẹ̀sílẹ̀ yíò dópin, tàbí pé yíò jẹ́ ohun tí ó tọ́ pé kí ìtàjẹ̀sílẹ̀ ẹranko dópin; ìgbànã ni òfin Mósè yíò wá sí ìmúṣẹ; bẹ̃ni, gbogbo rẹ̀ ni yíò wá sí ìmúṣẹ, pẹ̀lú èyítí ó kéré jùlọ, tí kò sì sí nínú nwọn tí yíò rékọjá láìmúṣẹ. Ẹ sì kíyèsĩ, èyí ni gbogbo ìtumọ̀ òfin nã, èyítí ó kére jùlọ nínú rẹ̀ ntọ́ka sí ìrúbọ nlá nnì tĩ ṣe àṣekẹ́hìn; ìrúbọ nlá tĩ ṣe àṣekẹ́hìn nã ni yíò sì jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bẹ̃ni, èyítí kò ní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin àti ayérayé. Ní ọ̀nà yĩ ni òun yíò sì fi ìgbàlà fún gbogbo ẹnití ó bá gbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; èyí sì ni èrèdí fún ìrúbọ àṣekẹ́hìn yĩ, láti mú ọ̀pọ̀ ãnú jáde wá, èyítí ó borí àìṣègbè, tí ó sì fún ọmọ ènìyàn ní ọ̀nà tí nwọn yíò fi ní ìgbàgbọ́ sí ìrònúpìwàdà. Báyĩ sì ni ãnú yíò ṣe san gbèsè fún àìsègbè, tí yíò sì fi ọwọ́ ãbò rẹ̀ yí nwọn ká, nígbàtí ẹnití kò bá ní ìgbàgbọ́ sí ìrònúpìwàdà yíò di ẹnití a ó fi gbogbo òfin tí ó rọ̀ mọ́ àìṣègbè mú; nítorínã ẹnití ó bá ní ìgbàgbọ́ sí ìrònúpìwàdà nìkan ni a ó fun ní ìlàna ìràpadà títóbi àti ti ayérayé nnì. Nítorínã kí Ọlọ́run fi fũn yín, ẹ̀yin arákùnrin mi, kí ẹ̀yin kí ó lè bẹrẹ sĩ lo ìgbàgbọ́ nyín sí ti ìrònúpìwàdà, kí ẹ̀yin kí ó lè bẹ̀rẹ̀sí képe orúkọ rẹ̀ mímọ́, kí òun kí ó sì ṣãnú fún nyín; Bẹ̃ni, ẹ kígbe pè é fún ãnú; nítorítí ó lágbára láti gbàlà. Bẹ̃ni, ẹ rẹ ara nyín sílẹ̀, kí ẹ sì tẹ̀síwájú nínú àdúrà síi. Ẹ kígbe pè é nígbàtí ẹ̀yin bá wà nínú oko nyín, bẹ̃ni, lórí gbogbo ẹran-ọ̀sìn nyín. Ẹ kígbe pẽ nínú ilé nyín, bẹ̃ni lórí gbogbo agbo-ilé nyín, ní òwúrọ̀, ọ̀sán àti àṣálẹ́. Bẹ̃ni, ẹ kígbe pè é fún ìdojúkọ agbára àwọn ọ̀tá nyín. Bẹ̃ni, ẹ kígbe pè é fún ìdojúkọ èṣù, ẹnití í ṣe ọ̀tá fún gbogbo òdodo. Ẹ kígbe pè é lórí ohun-ọ̀gbìn oko nyín, kí ẹ̀yin lè ṣe rere nípasẹ̀ nwọn. Ẹ kígbe lórí àwọn àgbo-ẹran inú pápá nyín, kí wọ́n lè pọ̀ síi. Ṣùgbọ́n èyí nìkan kọ́; ẹ̀yin gbọ́dọ̀ kó àníyàn ọkàn nyín jáde nínú iyàrá nyín làti ibi ìkọ̀kọ̀ nyín, àti nínú aginjù nyín. Bẹ̃ni, nígbàtí ẹ̀yin kò bá sì kígbe pe Olúwa, ẹ jẹ́ kí ọkàn nyín kún, kí ó sì fà síi ninu àdúrà láìsimi fún àlãfíà nyín, àti pẹ̀lú fún àlãfíà àwọn tí nwọ́n yí nyín ká. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo wí fún nyín, ẹ má rò pé gbogbo rẹ̀ ní èyí; nítorípé lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí, bí ẹ̀yin bá ṣe àìbìkítà fún àwọn aláìní, àti àwọn ti wọn wa ni ìhòhò, tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ àwọn aláìsàn àti àwọn tí ojú npọ́n wò, kí ẹ sì fifún ni nínú ohun ìní nyín, bí ẹ bá ní, fún àwọn tí ó ṣe aláìní—èmi wí fún nyín, tí ẹ̀yin kò bá ṣe èyíkéyĩ nínú àwọn nkan wọ̀nyí, ẹ kíyèsĩ, asán ni àdúrà nyín íṣe, kò sì já mọ́ nkankan, ẹ̀yin sì dàbí àwọn àgàbàgebè, tí nwọn a máa sẹ́ ìgbàgbọ́ nnì. Nítorínã, bí ẹ̀yin kò bá rántí láti máa fi ìfẹ́ lò, ẹ̀yin dàbí ìdàrọ́, èyítí àwọn tí ndá fàdákà dànù, (nítorítí kò wúlò fún ohunkóhun) tí ó sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ ènìyàn. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, ó wù mí pé lẹ́hìn tí ẹ ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí, níwọ̀n ìgbàtí àwọn ìwé-mímọ́ ti jẹ́rĩ sí àwọn ohun wọ̀nyí, ẹ dìde kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀sí so èso sí ti ìrònúpìwàdà. Bẹ̃ni, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó dìde, kí ẹ má sì sé ọkàn nyín le mọ́; nítorí ẹ kíyèsĩ, èyí ni àkokò àti ọjọ́ ìgbàlà nyín; àti nítorínã, bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà, tí ẹ kò sì sé ọkàn nyín le, lójúkannã ni Ọlọ́run yíò fún nyín ní ìpín nínú ìlànà ìràpadà títóbi àti ti ayérayé nnì. Nítorí ẹ kíyèsĩ, ìgbésí-ayé yĩ jẹ́ àkọkò tí ènìyàn níláti múrasílẹ̀ láti bá Ọlọ́run pàdé; bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, ọjọ́ ìgbésí-ayé yĩ ni ọjọ́ tí ènìyàn níláti ṣe iṣẹ́ wọn. Àti nísisìyí, bí èmi sì ti wí fún nyín ṣãjú, bí ẹ̀yin ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí, nítorínã, mo bẹ̀ nyín pé kí ẹ ṣíwọ́ ìfònídóní-fọ̀ladọ́la nípa ọjọ́ ìrònúpìwàdà nyín di ìgbà òpin; nítorípé lẹ́hin ọjọ́ ìgbésí-ayé yĩ, èyítí a fún wa láti múrasílẹ̀ fún ayérayé, ẹ kíyèsĩ, bí àwa kò bá lo àkokò wa ní ọ̀nà tí ó dára ní ìgbésí-ayẹ́ wa, ìgbà àṣálẹ́ nã yíò sì dé nínú èyítí a kò lè ṣiṣẹ́ kankan. Ẹ̀yin kò lè wípé, nígbàtí ẹ bá bọ́ sínú ipò búburú nnì, pé èmi yíò ronúpìwàdà, pé èmi yíò padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi. Rárá, ẹ̀yin kò lè wí báyĩ; nítorípé ẹ̀mí kannã nnì, èyítí ó ngbé inú ara nyín ní àkókò tí ẹ̀yin bá jáde kúrò nínú ayé yĩ, ẹ̀mí kannã nnì, yíò ní ágbára láti gbé inú nyín nínú ayé ayérayé nã. Ẹ sì kíyèsĩ, bí ẹ̀yin bá ṣe ìfònídóní-fọ̀ladọ́la nípa ọjọ́ ìrònúpìwàdà nyín àní títí ẹ ó fi kú, ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti fi ara nyín sí ábẹ́ ẹ̀mí tí íṣe ti èṣù, òun sì ti dè nyín mọ́ ara rẹ̀; nítorínã, Ẹ̀mí tí íṣe ti Olúwa ti fi nyín sílẹ̀, kò sì ní àyè mọ́ nínú nyín, èṣù ni ó sì ní gbogbo agbára lórí nyín; èyí sì ni ipò ìgbẹ̀hìn tí àwọn ènìyàn búburú yíò wà. Èyĩ ni èmi sì mọ̀, nítorípé Olúwa ti sọ wípé òun kò lè gbéinú tẹ́mpìlì àìmọ́, ṣùgbọ́n nínú ọkàn àwọn olódodo ni ó ngbé; bẹ̃ni, òun sì tún sọ pẹ̀lú pé àwọn olódodo yíò jókọ́ nínú ìjọba rẹ̀, tí nwọn kò sì ní jáde mọ́; ṣùgbọ́n tí a ó sọ aṣọ nwọn di funfun nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn nã. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí àwọn nkan wọ̀nyí, àti pé kí ẹ̀yin kí ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà nyín pẹ̀lú ìbẹ̀rù níwájú Ọlọ́run, kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe sẹ́ bíbọ̀wá Krístì mọ́; Pé kí ẹ̀yin máṣe bá Ẹ̀mí Mímọ́ ja ìjàkadì mọ́, ṣùgbọ́n pé kí ẹ̀yin kí ó gbã, kí ẹ sì gba orúkọ Krístì sí ayé nyín; pé kí ẹ̀yin kí ó rẹ ara nyín sílẹ̀ àní búrú-búrú, kí ẹ sì máa sin Ọlọ́run, ní ibi èyíówù tí ẹ lè wà, ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́; kí ẹ sì máa gbé ìgbé ayé ìmọ́re ní ojọ́júmọ́, fún ọ̀pọ̀ ãnú àti ìbùkún tí ó ndà sí órí yín. Bẹ̃ni, èmi sì tún gbà nyín níyànjú, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé kí ẹ máa ṣọ́ra nínú àdúrà láìsimi, pé kí a máṣe ti ipasẹ̀ àdánwò èṣù darí nyín kúrò, pé kí òun má bã lè borí nyín, pé kí ẹ̀yin má bã wà lábẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹhìn; nítorí ẹ kíyèsĩ, òun kò lè san ohun rere kan fún nyín. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi ìbá gbà nyín níyànjú pé kí ẹ ní sũrù, àti pé kí ẹ faradà onírurú ìpọ́njú; pé kí ẹ máṣe bú àwọn wọnnì tí nwọ́n lée nyín jáde nítorí ipò tálákà tí ẹ̀yin wà, èyítí ó tayọ, kí ẹ̀yin ó má bã di ẹlẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn nã; Ṣùgbọ́n pé kí ẹ̀yin kí ó ní sũrù, kí ẹ sì faradà àwọn ìpọ́njú nnì, pẹ̀lú ìrètí nlá pé ní ọjọ́ kan ẹ̀yin yíò sinmi kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú nyín. 35 Ìwãsù ọ̀rọ̀ nã pa ìwà-àrékérekè àwọn ará Sórámù run—Nwọ́n lé àwọn tí a ti yí lọ́kàn padà jáde, tí nwọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ámọ́nì ní Jẹ́ṣónì—Álmà kẹ́dùn ọkàn nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn nã. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyĩ ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ámúlẹ́kì ti fi òpin sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ni nwọ́n kúrò lãrín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, tí nwọ́n sì kọjá lọ sínú ilẹ̀ Jẹ́ṣónì. Bẹ̃ ni, àti àwọn arákùnrin ìyókù, lẹ́hìn tí nwọ́n ti wãsù ọ̀rọ̀ nã fún àwọn ará Sórámù, àwọn nã kọjá lọ sínú ilẹ̀ Jẹ́ṣónì. Ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí àwọn olórí àwọn ará Sórámu t i pèròpọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti fi wãsù fún nwọn, nwọ́n bínú nítorí ọ̀rọ̀ nã, nítorítí ó pa ìwà-àrekérekè nwọn run; nítorínã ni nwọ́n kò ṣe lè fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ nã. Nwọ́n sì ránṣẹ́ nwọ́n sì pe gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ nã jọ, nwọ́n sì pèròpọ̀ pẹ̀lú nwọn nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ tẹ́lẹ̀. Nísisìyí, àwọn olórí nwọn àti àwọn àlùfã nwọn àti àwọn olùkọ́ni nwọn kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn nã mọ̀ nípa ìfẹ́-inú nwọn; nítorínã, nwọ́n ṣe ìwádĩ ní ìkọ̀kọ̀ nípa èrò ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn nã. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí nwọ́n ti mọ́ èrò ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn nã, ni nwọ́n lé àwọn tí nwọn ní inú dídùn sí ọ̀rọ̀ Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde kúrò nínú ilẹ̀nã; wọn sì pọ̀; nwọ́n sì kọjá lọ sínú ilẹ̀ Jẹ́ṣónì. Ó sì ṣe tí Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣe ìtọ́jú nwọn. Nísisìyí àwọn ará Sórámù bínú sí àwọn ènìyàn Ámọ́nì tí nwọ́n wà ní Jẹ́ṣónì, àti pé olórí aláṣẹ àwọn ará Sórámù, ẹnití ó jẹ́ ènìyàn búburú púpọ̀, ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn Ámọ́nì pé òun fẹ́ kí nwọ́n lé gbogbo àwọn tí nwọn kọjá wá láti ọ̀dọ̀ nwọn sínú ilẹ̀ nwọn jáde. Ó sì nsọ ọ̀rọ̀ ìdẹ́rùbani púpọ̀ nípa nwọn. Àti nísisìyí àwọn ènìyàn Ámọ́nì kò sì bẹ̀rù ọ̀rọ̀ nwọn; nítorínã nwọ́n kò lé nwọn jáde, ṣùgbọ́n nwọ́n gba gbogbo àwọn tálákà tí ó wà nínú àwọn ará Sórámù tí nwọ́n kọjá wá sọ́dọ̀ nwọn; nwọ́n sì bọ́ nwọn, nwọ́n sì fi aṣọ bò nwọ́n lára, nwọ́n sì fún nwọn ní ilẹ̀ fún ìní nwọn; nwọ́n sì fi fún nwọn gẹ́gẹ́bí nwọ́n ti ṣe aláìní. Nísisìyí, eleyĩ mú kí inú àwọn ará Sórámù rú sókè ní ìbínú sí àwọn ènìyàn Ámọ́nì, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí darapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì, tí nwọ́n sì rú àwọn nã sókè ní ìbínú sí nwọn. Báyĩ sì ni àwọn ará Sórámù àti àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìmúrasílẹ̀ fún àti jagun pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ámọ́nì, àti pẹ̀lú àwọn ará Nífáì nã. Báyĩ sì ni ọdún kẹtàdínlógún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin. Àwọn ènìyàn Ámọ́nì sì jáde kúrò nínú ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, nwọ́n sì wọ inú ilẹ̀ Mẹ́lẹ́kì, nwọ́n sì fún àwọn ọmọ ogun àwọn ará Nífáì ní ãyè nínú ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, kí nwọ́n lè bá àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì àti ti àwọn ará Sórámù jà; báyĩ sì ni ogun bẹ̀rẹ̀ lãrín àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Nífáì, ní ọdún kejìdínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́; a ó sì sọ nípa àwọn ogun tí nwọ́n jà lẹ́hìn èyí. Álmà àti Ámọ́nì, àti àwọn arákùnrin nwọn, àti àwọn ọmọ Álmà méjì sì padà lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, lẹ́hìn tí nwọ́n ti jẹ́ ohun èlò lọ́wọ́ Ọlọ́run láti mú púpọ̀ nínú àwọn ará Sórámù wá sí ìrònúpìwàdà; gbogbo àwọn tí nwọn sì rònúpìwàdà nwọn ni nwọ́n lé jáde kúrò nínú ilẹ̀ nwọn; ṣùgbọ́n nwọ́n ní ilẹ̀ fún ìní nwọn nínú orí ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, nwọ́n sì ti gbé ohun-ìjà ogun láti dãbò bò ara nwọn, àti àwọn aya nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn, àti ilẹ̀ nwọn gbogbo. Nísisìyí, nítorípé Álmà kẹ́dùn fún ìwà-àìṣedẽdé àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̃ni fún àwọn ogun, àti àwọn ìtàjẹ̀sílẹ̀, àti àwọn ìjà tí ó wà lãrín nwọn; àti nítorípé ó níláti kéde ọ̀rọ̀ nã, tàbí pé a ti rán an láti kéde ọ̀rọ̀ nã, lãrín gbogbo ènìyàn nínú ìlú gbogbo; àti nítorípé ó ríi pé àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí sé ọkàn nwọn le, àti pé nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí bínú nítorí àìṣegbé ọ̀rọ̀ nã, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi. Nítorínã, ó mú kí àwọn ọmọ rẹ̀ kóra nwọn jọ, pé kí òun lè fún olúkúlùkù nwọn ní ìmọ̀ràn tirẹ̀, lọ́tọ̣́tọ̀, nípa àwọn ohun tĩ ṣe ti òdodo. A sì ní ìkọsílẹ̀ nípa àwọn òfin rẹ̀, èyítí ó fún nwọn gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ti ara rẹ̀. Àwọn òfin Álmà sí ọmọ rẹ̀ Hẹ́lámánì. Èyítí a kọ sí àwọn orí 36 àti 37. 36 Álmà jẹ́rĩ sí Hẹ́lámánì nípa ti ìyílókànpadà rẹ̀ lẹ́hìn tí ó rí ángẹ́lì kan—Ó jìyà ìrora ẹni-ìdálẹ́bi; ó képe orúkọ Jésù, a sì bí nipa ti Ọlọ́run lẹ́hìnnã—Ayọ̀ dídùn kún ọkan rẹ̀—Ó rí àjọ àìníye àwọn ángẹ́lì tí nwọ́n n yin Ọlọ́run—Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí nwọn di ẹniìyílọ́kànpadà ni wọ́n ti tọ́wò ti wọ́n sì ti rí bí òun ti tọ́wò tí ó sì ti rí. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Ọmọ mi, fi etí sí ọ̀rọ̀ mi; nítorítí èmi ṣe ìbúra pẹ̀lú rẹ, pé níwọ̀n ìgbàtí ìwọ bá pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ìwọ yíò ṣe rere lórí ilẹ̀ yĩ. Èmi fẹ́ kí ìwọ kí ó ṣe gẹ́gẹ́bí èmi ti ṣe, ní ti rírántí ìgbèkùn àwọn bàbá wa; nítorítí nwọ́n wà nínú oko-ẹrú, tí kò sì sí ẹnití ó lè kó nwọn yọ bí kò ṣe Ọlọ́run Ábráhámù, àti Ọlọ́run Ísãkì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù; òun sì kó nwọn yọ kúrò nínú ìpọ́njú nwọn gbogbo nítọ́tọ́. Àti nísisìyí, A! ọmọ mi, Hẹ́lámánì, kíyèsĩ, ìwọ wà ní èwe rẹ, nítorínã, mo bẹ̀ ọ́ pé kí ìwọ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi, kí ìwọ kí ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorítí èmi mọ̀ wípé ẹnìkẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run yíò rí ìrànlọ́wọ́ nínú gbogbo àdánwò wọn; àti lãlã wọn, àti ìpọ́njú wọn, tí a ó sì gbé e sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn. Àti pẹ̀lú pé èmi kò fẹ́ kí ìwọ rò pé èmi mọ̀ ohun yĩ fúnra mi—kĩ ṣe nípasẹ̀ ti ayé yĩ, bíkòṣe nípasẹ̀ ti ẹ̀mí, kĩ ṣe nípasẹ̀ ti ara bíkòṣe nípasẹ̀ ti Ọlọ́run. Nísisìyí, kíyèsĩ, èmi wí fún ọ́, tí a kò bá bí mi nípa ti Ọlọ́run, èmi kì bá tí mọ̀ àwọn nkan wọ̀nyí; ṣùgbọ́n Ọlọ́run, láti ẹnu àwọn ángẹ́lì rẹ̀ mímọ́, ti sọ àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀ fún mi, kĩ ṣe nítorí wíwà ní yíyẹ mi; Nítorítí èmi nlọ kiri pẹ̀lú àwọn ọmọ Mòsíà, tí à npète láti pa ìjọ-Ọlọ́run run; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Ọlọ́run rán ángẹ́lì rẹ̀ mímọ́ láti dá wa dúró lójú ọ̀nà ìrìn-àjò wa. Sì kíyèsĩ, ó bá wa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn èyítí ó dàbí sísán àrá, gbogbo ilẹ̀ sì mì lábẹ́ ẹsẹ̀ wa; àwa sì ṣùbú lulẹ̀, nítorítí ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá sí orí wa. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ohùn nã sọ fún mi pé: Dìde. Èmi sì dìde dúró, mo sì rí ángẹ́lì nã. Òun sì wí fún mi pé: Bí ìwọ kò bá fẹ́ ìparun ara rẹ, dáwọ́dúró ìlépa láti pa ìjọ-Ọlọ́run run. Ó sì ṣe tí èmi ṣubú lulẹ̀; èyí sì jẹ́ fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta àti òru mẹ́ta tí èmi kò fi lè la ẹnu mi, bẹ̃ nã ni èmi kò lè gbé apá tàbí ẹsẹ̀ mi. Ángẹ́lì nã sì tún bá mi sọ̀rọ̀ síwájú síi, èyítí àwọn arákùnrin mi gbọ́, ṣùgbọ́n tí èmi kò gbọ́ nwọn; nítorípé nígbàtí èmi gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí—Bí ìwọ kò bá fẹ́ ìparun ara à rẹ̀, dáwọ́dúró lílépa láti pa ìjọ-Ọlọ́run run—Ẹ̀rù nlá bà mí pẹ̀lú ìyàlẹ́nú pé bóyá a ó pa mi run, tí èmi sì ṣubú lulẹ̀ tí èmi kò sì gbọ́ ohun kankan mọ́. Ṣùgbọ́n oró ayérayé gbò mí, nítorítí ìforó bá ọkàn mi èyítí ó ga jùlọ tí ó sì gbò ó pẹ̀lú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi. Bẹ̃ni, èmi rántí gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedẽdé mi, fun eyiti adami lóró pẹ̀lú ìrora ọ̀run-àpãdì; bẹ̃ni, èmi ríi pé mo ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run mi, tí èmi kò sì tún pa àwọn òfin rẹ̀ mímọ́ mọ́. Bẹ̃ni, tí èmi sì ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, tàbí kí a wípé mo ti dári wọn lọ sí ìparun; bẹ̃ni, àti ní kúkúrú, púpọ̀ ni àìṣedẽdé mí ti jẹ́, tí èrò wíwá síwájú Ọlọ́run mi gbò ẹ̀mí mi pẹ̀lú ìbẹ̀rù tí a kò lè máa sọ. A!, èmi rọ́, wípé, ìbá ṣeéṣe kí a lé mi kúrò, kí èmi sì di aláìsí ní ẹ̀mí àti ní ara, kí a máa lè mú mi wá dúró níwájú Ọlọ́run mi, fún ìdájọ́ lórí àwọn ìṣe mi. Àti nísisìyí, fún ọjọ́ mẹ́ta àti òru mẹ́ta ni èmi fi wà ní gbígbò, àní pẹ̀lú ìrora ẹni-ìdálẹ́bi. Ó sì ṣe bí oró yĩ ṣe ngbò mí, bí mo sì ṣe wà nínú ìforó ọkàn nípa ìrántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi púpọ̀, kíyèsĩ, mo rántí pẹ̀lú pé mo gbọ́ tí bàbá mi ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn nã nípa bíbọ̀wá ẹnìkan tí à npè ní Jésù Krístì, tí íṣe Ọmọ Ọlọ́run, láti ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgbáyé. Nísisìyí, nígbàtí ọkàn mi tẹ̀ mọ́ èrò yĩ, mo kígbe nínú ọkàn mi pé: A! Jésù, ìwọ Ọmọ Ọlọ́run, ṣãnú fún mi, tí mo wà nínú ipò ìkorò òrọ́ró, ti a si yi mi ka pẹlũ ẹ̀wọ̀n ainipẹkun ti ikú. Àti, nísisìyí, kíyèsĩ, nígbàtí mo ronú nípa èyí, èmi kò rántí àwọn ìrora mi mọ́; bẹ̃ ni, ìrántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi kò gbò mí mọ́. Àti, a!, irú ayọ̀ wo, àti pé irú ìmọ́lẹ̀ wo ni èmi rí; bẹ̃ni, ọkan mi kún fún ayọ̀ èyítí ó pọ̀ púpọ̀ bí ìrora èyítí mo ní ṣãjú! Bẹ̃ni, èmi wí fún ọ, ìwọ ọmọ mi, pé kò sí ohun tí ó lè tayọ ìkorò ìrora mi. Bẹ̃ni, èmi sì tún wí fún ọ́, ìwọ ọmọ mi, pé ní ìdà kejì, kò sí ohun tí ó lè tayọ adùn àti ayọ̀ tí mo ní. Bẹ̃ni, èmi rò pé mo rí, àní gẹ́gẹ́bí bàbá wa Léhì ti ríi, tí ó rí Ọlọ́run tí ó jókọ́ lórí ìtẹ́-ọba rẹ̀, tí àjọ àìníye àwọn ángẹ́lì sì yíi ká ní ìwà kíkọrin àti yíyin Ọlọ́run nwọn; bẹ̃ni, ọkàn mi sì fẹ́ láti wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, apá àti ẹsẹ̀ mi sì tún mókun, èmi sì dúró lórí ẹsẹ̀ mi, tí mo sì fi han àwọn ènìyàn nã pé a ti bí mi nípa ti Ọlọ́run. Bẹ̃ni, láti ìgbà nã lọ àti títí di ìsisìyí pẹ̀lú, èmi ti ṣiṣẹ́ láìsinmi, kí èmi kí ó lè mú àwọn ọkàn wá sí ìronúpìwàdà; kí èmi kí ó lè mú nwọn tó wò nínú ọ̀pọ̀ ayọ̀ nínú èyítí èmi ti tọ́ wò; kí a lè bí wọn nípa ti Ọlọ́run pẹ̀lú, kí nwọ́n sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Bẹ̃ni, àti nísisìyí kíyèsĩ, A! ọmọ mi, Olúwa ti fún mi ní ọ̀pọ̀ ayọ̀ nlá nínú èrè iṣẹ́ mi; Nítorí tí ọ̀rọ̀ èyítí òun ti fi fún mí, kíyèsĩ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ti bí nípa ti Ọlọ́run, tí nwọ́n sì ti tọ wò gẹ́gẹ́bí èmi ti tọ wò, tí wọ́n sì ti rí ní ójúkojú gẹ́gẹ́bí èmi ti rí; nítorínã nwọn mọ̀ nípa àwọn ohun wọnyi tí èmi ti sọ nípa nwọn, gẹ́gẹ́bí èmi ṣe mọ̀; ìmọ̀ tí èmi ní jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Èmi sì ti rí ìrànlọ́wọ́ gbà nínú àdánwò àti ìyọnu onírũrú, bẹ̃ni, àti onírũrú ìpọ́njú; bẹ̃ni, Ọlọ́run ti yọ mí kúrò nínú ìdè, àti kúrò nínú ikú; bẹ̃ni, èmi sì gbẹ́kẹ̀ mi lé e, òun yíò sì kó mi yọ síbẹ̀. Èmi sì mọ̀ wípé òun yíò gbé mi dìde ní ọjọ́ ìkẹhìn, láti gbé pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo; bẹ̃ni, èmi yíòsì máa yìn ín títí láé, nítorítí ó ti mú àwọn bàbá wa jáde kúrò ní Égíptì, ó sì ti gbé àwọn ará Égíptì mì nínú Òkun Pupa; òun sì darí nwọn nípa agbára rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ ìlérí nã; bẹ̃ni, òun sì ti kó nwọn yọ kúrò nínú oko-ẹrú àti ìgbèkùn láti ìgbà dé ìgbà. Bẹ̃ni, òun sì tún mú àwọn bàbá wa jáde kúrò nínú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù; òun sì tún ti gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú àti ìgbèkùn, nípa agbára rẹ̀ àìlópin, láti ìgbàdé ìgbà, àní títí di àkokò yĩ; èmi a sì máa rántí àkokò ìgbèkùn nwọn; bẹ̃ni, ó sì yẹ kí ẹ̀yin nã máa rántí àkokò ìgbèkùn nwọn, gẹ́gẹ́bí èmi ti ṣe. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ọmọ mi, èyí nìkan kọ́; nítorítí ó yẹ kí ìwọ mọ̀, gẹ́gẹ́bí èmi ti mọ̀, pé níwọ̀n ìgbà tí ìwọ bá pa òfin Ọlọ́run mọ́ ìwọ yíò ṣe rere ní ilẹ̀ nã; ó sì yẹ kí ìwọ mọ̀ pẹ̀lú, pé níwọ̀n ìgbàtí ìwọ kò bá pa òfin Ọlọ́run mọ́, a ó ke ọ́ kúrò níwájú rẹ̀. Nísisìyí èyí jẹ́ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀. 37 Àwọn àwo idẹ pẹ̀lú àwọn ìwé-mímọ́ míràn ni a tọ́jú pamọ́ lati mú ọkàn wá sí ìgbàlà—Àwọn ará Járẹ́dì ni a parun nítorí ìwà búburú nwọn—Àwọn ìmùlẹ̀ ìkọ̀kọ̀ àti májẹ̀mú nwọn níláti wà ní pípamọ́ kúrò lãrín àwọn ènìyàn nã—Gba ìmọ̀ràn Olúwa nínú ohun gbogbo tí ìwọ bá nṣe—Gẹ́gẹ́bí Liahónà ṣe tọ́ àwọn ará Nífáì sọ́nà, bẹ̃ nã ni ọ̀rọ̀ Krístì ṣe ndarí ènìyàn sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ọmọ mi Hẹ́lámánì, mo pã láṣẹ fún ọ pé kí o gbé àwọn àkọsílẹ̀ nã èyítí a ti fi lé mi lọ́wọ́; Èmi sì tún pã láṣẹ fún ọ pé kí ìwọ kí ó ṣe àkọsílẹ̀ nípa àwọn ènìyàn yĩ, gẹ́gẹ́bí èmi ti ṣe, lé orí àwọn àwo ti Nífáì, kí o sì pa àwọn ohun wọ̀nyí mọ́ ní mímọ́, èyítí èmi ti pa mọ́, àní ní ìbámu pẹ̀lú bí èmi ti ṣe ṣe ìpamọ́ nwọn; nítorí pé fún ìdí ọgbọ́n ni a ṣe nṣe ìpamọ́ nwọn. Àwọn àwo idẹ wọ̀nyí èyítí ó ní àwọn ìfín wọ̀nyí, èyítí ó ní àwọn àkọsílẹ̀ nípa àwọn ìwémímọ́ lórí nwọn, èyítí ó ní ìtàn ìdílé àwọn bàbá nlá wa, àní láti ìbẹ̀rẹ̀— Kíyèsĩ, àwọn bàbá wa ti sọọ́ tẹ́lẹ̀ pé kí a pa nwọ́n mọ́, kí a sì fi nwọ́n lè ọwọ́ àwọn ọmọ wa láti ìran kan dé òmíràn, pé kí a pa nwọ́n mọ́, kí a sì ṣe ìtọ́jú nwọn nípasẹ̀ ọwọ́ Olúwa títí nwọn ó fi tàn ká gbogbo orílẹ̀èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn, pé kí nwọ́n lè mọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ tí ó wà lórí nwọn. Àti nísisìyí kíyèsĩ, bí a bá pa nwọn mọ, nwọ́n níláti wà ní dídán; bẹ̃ni, nwọn ó sì wà ní dídán; àní, bẹ̃ sì ní gbogbo àwọn àwo nã ti a kọ àwọn ohun mímọ́ sí. Nísisìyí ìwọ lè rò wípé ohun aláìgbọ́n ní èyí jẹ́ fún mi láti ṣe; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi wí fún ọ, pé nípa àwọn ohun kékèké tí ó sì rọrùn ní àwọn ohun nlá tí njáde wa; àti pé àwọn ohun kékèké ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà a máa dàmú ọlọgbọ́n. Olúwa Ọlọ́run a sì máa ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà èyítí yíò mú ìpinnu nlá rẹ̀ tĩ ṣe ti ayérayé ṣẹ; àti pé nípaohun tí ó kéré púpọ̀ Olúwa a máa dàmú ọlọgbọ́n tí yìó sì mú ìgbàlà bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkan. Àti nísisìyí, ní tẹ́lẹ̀rí ó jẹ́ ohun ọgbọ́n nínú Ọlọ́run pé kí a fi àwọn ohun wọ̀nyí sí ìpamọ́; nítorí kíyèsĩ, nwọ́n ti ṣí àwọn ènìyàn yĩ ní iyè, bẹ̃ni, nwọ́n sì ti jẹ́ kí púpọ̀ mọ́ ìkùnà ọ̀nà nwọn, nwọ́n sì ti mú nwọn wá sí ìmọ̀ Ọlọ́run nwọn sí ìgbàlà ọkàn nwọn. Bẹ̃ni, èmi wí fún ọ, bíkòbáṣe ti àwọn ohun wọ̀nyí ti àwọn àkọsílẹ̀ yĩ ní nínú, èyítí ó wà lórí àwọn àwo wọ̀nyí, Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kì bá tí lè yí ẹgbẽgbẹ̀rún púpọ̀ àwọn ará Lámánì padà nínú àìtọ̀nà àṣà àwọn bàbá nwọn; bẹ̃ni, àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí àti ọ̀rọ̀ nwọn mú nwọn wà sí ìrònúpìwàdà; èyí já sí pé, nwọ́n mú nwọn bọ́ sínú ìmọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn, àti láti yọ̀ nínú Jésù Krístì Olùràpadà nwọn. Tani ẹnití ó mọ̀ bóyá àwọn ni yíò mú ọ̀pọ̀ ẹgbẽgbẹ̀rún nwọn, bẹ̃ni, àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ẹgbẽgbẹ̀rún àwọn arákùnrin wa ọlọ́rùnlíle, àwọn ará Nífáì, tí nwọn nṣe ọkàn nwọn le nísisìyí nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedẽdé, bọ́ sínú ìmọ̀ Olùràpadà nwọn? Nísisìyí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ yĩ kò tĩ di mímọ̀ fún mi pátápátá; nítorínã èmi yíò dánu dúró. Ó sì tó bí èmi bá sọ wípé a tọ́jú nwọn pamọ́ fún ìdí ọgbọ́n, ìdí èyítí ó jẹ́ mímọ̀ fún Ọlọ́run; nítorítí ó nṣàkóso pẹ̀lú ọgbọ́n lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ọ̀nà rẹ̀ gbogbo ni ó sì tọ́, tí ipa rẹ̀ jẹ́ ọ̀na àìyípadà ayérayé kan. A! rántí, rántí ò, ọmọ mi Hẹ́lámánì, bí àwọn òfin Ọlọ́run ṣe múná tó. Òun sì wípé: Bí ìwọ bá pa òfin mi mọ́, ìwọ yíò ṣe rere lórí ilẹ̀ nã—ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá pa òfin rẹ̀ mọ́, a ó ké ọ kúrò níwájú rẹ̀. Àti nísisìyí kí o sì rántí, ọmọ mi, pé Ọlọ́run ti fi ohun wọ̀nyí tĩ ṣe mímọ́ lé ọ lọ́wọ́, èyítí o ti pamọ́ ní mímọ́, àti pẹ̀lú ti yíò pamọ́ ní ìtọ́jú fún ìdí ọgbọ́n nínú rẹ̀, kí ó lè fi agbára rẹ̀ hàn fún àwọn ìran tí nbọ̀wá. Àti nísisìyí kíyèsĩ, mo wí fún ọ nípasẹ̀ ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀, pé bí ìwọ bá rékọjá sí òfin Ọlọ́run, kíyèsĩ, a ó gba àwọn ohun wọ̀nyí tí nwọ́n jẹ́ mímọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ nípa agbára Ọlọ́run, a ó sì fi ọ́ lé Sátánì lọ́wọ́, tí òun yíò sì kù ọ́ bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, tí ìwọ ṣe gẹ́gẹ́bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún ọ lórí àwọn ohun wọ̀nyí tí nwọn í ṣe mímọ́, (nítorítí o níláti bẹ Olúwa fún ohun gbogbo èyíkéyĩ tí ìwọ yíò ṣe pẹ̀lú nwọn) kíyèsĩ, kò sí agbára ayé tàbí ti ọ̀run àpãdì tí ó lè gbà nwọn lọ́wọ́ rẹ, nítorítí Ọlọ́run lágbára tóbẹ̃ tí yíò fi mú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Nítorítí òun yíò mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ èyítí oun yio ṣe pẹ̀lú rẹ, nítorítí òun ti mú àwọn ìlérí tí ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn bàbá wa ṣẹ. Nítorítí ó ṣe ìlérí fún nwọn pé òun yíò tọ́jú àwọn ohun wọ̀nyí pamọ́ fún ìdí ọgbọ́n nínú rẹ̀, kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ hàn fún àwọn ìran tí nbọ̀wá. Àti nísisìyí kíyèsĩ, ìdí kan ni ó ti mú ṣẹ, àní sí ìdápadà bọ̀sípò ọ̀pọ̀ ẹgbẽgbẹ̀rún àwọn ará Lámánì sí ìmọ̀ òtítọ́; òun sìti fi agbára rẹ̀ hàn, òun yíò sì tún fi agbára rẹ̀ hàn nípasẹ̀ àwọn ohun wọ̀nyí sí àwọn ìran tí nbọ̀wá; nítorínã a ó pa àwọn ohun wọ̀nyí mọ́. Nítorínã mo pàṣẹ fún ọ, ọmọ mi Hẹ́lámánì, pé kí o tẹramọ́ imúṣẹ ọ̀rọ̀ mi, àti pé kí ìwọ kí ó tẹramọ́ pípa òfin Ọlọ́run mọ́ gẹ́gẹ́bí a ti kọ nwọ́n. Àti nísisìyí, èmi yíò sì bá ọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn àwo mẹ́rìnlélógún nnì, pé kí o pa nwọ́n mọ́, kí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nnì àti àwọn iṣẹ́ òkùnkùn, àti àwọn iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ nwọn, tàbí iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn nnì tí a ti parun, kí ó di mímọ̀ fún àwọn ènìyàn yĩ; bẹ̃ni, gbogbo ìpànìyàn nwọn, àti olè jíjà, àti ìkógun nwọn, àti ìwà búburú nwọn àti ìwà ẽrí nwọn, lè di mímọ̀ sí àwọn ènìyàn yìi; bẹ̃ni, àti pé kí o tọ́jú àwọn atúmọ̀ yĩ pamọ́. Nìtorí kíyèsĩ, Olúwa ríi pé àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀sí ṣiṣẹ́ ní òkùnkùn, bẹ̃ni, nwọ́n nṣe ìpànìyàn ní ìkọ̀kọ̀ àti ìwà ẽrí; nítorínã Olúwa wípé, bí nwọn kò bá ronúpìwàdà a ó pa nwọ́n run kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Olúwa sì wípé: Èmi yíò pèsè fún ìránṣẹ́ mi Gásélémù, òkúta kan, èyítí yíò tanná jáde nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, kí èmi lè fi han àwọn ènìyàn mi tí nwọn nsìn mí, kí èmi lè fi iṣẹ́ ọwọ́ àwọn arákùnrin nwọn hàn nwọ́n, bẹ̃ni, iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ nwọn, àti iṣẹ́ òkùnkùn wọn, àti ìwà búburú àti ohun ìríra nwọn. Àti nísisìyí, ọmọ mi, àwọn atúmọ̀ wọ̀nyí ni a pèsè kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ṣẹ, èyítí ó ti sọ, tí ó wípé: Èmi yíò mú jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ gbogbo iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ nwọn àti ìwà ẽrí nwọn; àti pé bí nwọn kò bá ronúpìwàdà èmi yíò pa nwọ́n run kúrò lórí ilè ayé; èmi yíò sì fi gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ àti ẽrí nwọn hàn sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí yíò ní ilẹ̀ nã ní ìní lẹ́hìn èyí. Àti nísisìyí, ọmọ mi, àwa ríi pé nwọn kò ronúpìwàdà; nítorínã a ti pa nwọ́n run, àti pé títí di àkokò yĩ, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ti ṣẹ; bẹ̃ni, ohun ẽrí nwọn ìkọ̀kọ̀ ni a ti mú jáde kúrò nínú òkùnkùn tí a sì ti sọ di mímọ̀ fún wa. Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo pàa láṣẹ fún ọ́ pé kí ìwọ kí ó fi sí àkóso rẹ gbogbo ìbúra nwọn, àti àwọn májẹ̀mú nwọn, àti àwọn àdéhùn nwọn tí nwọ́n ṣe nínú ìwà ẽrí ìkọ̀kọ̀ nwọn; bẹ̃ni, àti gbogbo ohun àmì àti ìyanu nwọn ni ìwọ yíò pamọ́ kúrò ní mímọ̀ sí àwọn ènìyàn yĩ, kí nwọn má lè mọ̀ nwọ́n, pé bóyá nwọ́n lè ṣubú sínú ìwà búburú, tí nwọn ó sì parun. Nítorí kíyèsĩ, ègún wà lórí gbogbo ilẹ̀ yĩ, pé ìparun yíò wá sí órí gbogbo àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn, ní ìbámu pẹ̀lú agbára Ọlọ́run, nígbàtí nwọ́n bá ti gbó nínú ìwà búburú nwọn; nítorínã ó jẹ́ ìfẹ́-inú mi kí àwọn ènìyàn yìi máṣe parun. Nítorínã ìwọ yíò pa àwọn ìlànà ìkọ̀kọ̀ ti ìbúra àti májẹ̀mú nwọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn yĩ, àwọn ìwà búburú nwọn àti àwọn ìwà ìpànìyàn nwọn àti àwọn ìwà ẽrí nwọn nìkan ni ìwọ yíò jẹ́ kí nwọ́n mọ̀; ìwọ yíò sì kọ́ nwọn láti ní ìkórira fún irú ìwà búburú bẹ̃ àti ìwà ẽríàti ìwà ìpànìyàn; ìwọ yíò sì kọ́ nwọn pẹ̀lú pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a parun nípasẹ̀ ìwà búburú nwọn àti ìwà ẽrí àti ìwà ìpànìyàn nwọn. Sì kíyèsĩ nwọn pa gbogbo àwọn wòlĩ Olúwa tí nwọ́n wá sí ãrin nwọn láti kéde sí nwọn ní ti ìwà àìṣedẽdé nwọn; ẹ̀jẹ̀ àwọn tí nwọ́n pa sì nké sí Olúwa Ọlọ́run nwọn fún ẹ̀san lórí àwọn tí ó pa nwọ́n; bẹ̃ sì ni ìdájọ́ Ọlọ́run wá sí órí àwọn oníṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ àti ẹgbẹ́ òkùnkùn. Bẹ̃ni, ẹ̀gún sì wà lórí ilẹ̀ nã títí láéláé àti láéláé fún àwọn oníṣẹ́ ìkọkọ àti ẹgbẹ́ okunkun, àní sí ìparun, àfi bí nwọ́n bá ronúpìwàdà kí nwọ́n tó gbó sínú ìwà búburú. Àti nísisìyí, ọmọ mi, rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ; máṣe fi àwọn ìlànà ìkọ̀kọ̀ nnì hàn sí àwọn ènìyàn yĩ, ṣùgbọ́n kọ́ nwọn ní ìkórira ayérayé fún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedẽdé. Wãsù ìrònúpìwàdà sí wọn, àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì Olúwa; kọ́ nwọn láti rẹ ara nwọn sílẹ̀, àti láti jẹ́ oníwàtútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ènìyàn; kọ́ nwọn láti tako gbogbo àdánwò èṣù, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nwọn nínú Jésù Krístì Olúwa. Kọ́ nwọn láti má ṣãrẹ̀ iṣẹ́ rere ní ṣíṣe, ṣùgbọ́n kí nwọ́n jẹ́ oníwàtútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ènìyàn; nítorípé irú ẹni báyĩ ni yíò rí ìsinmi fún ọkàn nwọn. A!, rántí, ọmọ mi, kí o sì kọ́ ọgbọ́n ní ìgbà èwe rẹ; bẹ̃ni, kọ́ ní ìgbà èwe rẹ̀ láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Bẹ̃ni, kí o sì ké pe Ọlọ́run fún gbogbo ìrànlọ́wọ́ rẹ; bẹ̃ni, jẹ́ kí gbogbo ìṣe rẹ jẹ́ ti Olúwa, ibikíbi ti ìwọ bá sì lọ, jẹ́ kí ó jẹ́ nínú Olúwa; bẹ̃ni, jẹ́ kí gbogbo èrò ọkàn rẹ kọjúsí Olúwa; bẹ̃ni, jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ dúró lé Olúwa títí láé. Da ìmọ̀ràn pẹ̀lú Olúwa nínú ohun gbogbo tí ìwọ bá nṣe, òun yíò sì tọ́ ọ sọ́nà fún rere; bẹ̃ni, nígbàtí ìwọ bá dùbúlẹ̀ ní alẹ́, dùbúlẹ̀ sí ipa ti Olúwa, kí òun kí ó lè fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ ọ nínú ọ́run rẹ; nígbàtí ìwọ bá sì dìde ní òwúrọ̀, jẹ́ kí ọ̀kan rẹ̀ kún fún ọpẹ̀ sí Ọlọ́run; bí ìwọ bá sì ṣe àwọn ohun wọ̀nyí, a ó gbé ọ sókè ní ọjọ́ ìkẹ́hìn. Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo ní ohun kan láti sọ nípa ohun tí àwọn bàbá wa pè ní bọ̣́lù, tàbí afọ̀nàhàn—tàbí tí àwọn bàbá wa pẽ ní Liahónà, èyítí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ olùtọ́sọ́nà; Olúwa ni ó sì pèsè rẹ̀. Sí kíyèsĩ, kò sì sí ẹnìkẹ́ni tí ó lè ṣe irú iṣẹ́ ọnà aláràbarà dáradára báyĩ. Sì kíyèsĩ, a pèsè rẹ̀ láti fi hàn àwọn bàbá wa ipa ọ̀nà tí nwọn yíò rìn nínú aginjù. Ó sì ṣiṣẹ́ fún nwọn gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ nwọn nínú Ọlọ́run; nítorínã, bí nwọ́n bá ní ìgbàgbọ́ láti gbàgbọ́ pé Ọlọ́run lè mú kí àwọn kẹ̀kẹ́ nã kọjú sí ọ̀nà tí ó yẹ kí nwọ́n gba, kíyèsĩ, bẹ̃ ni ó rí; nítorínã, nwọn ní iṣẹ́ ìyanu yĩ, àti àwọn iṣẹ́ ìyanu míràn pẹ̀lú èyítí agbára Ọlọ́run múwá, lójojúmọ́. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nítorípé àwọn iṣẹ́ ìyanu nã wá nípasẹ̀ àwọn ohun kékèké, ó fi ohun ìyanu hàn nwọ́n. Nwọ́n yọ̀lẹ, nwọ́n sì gbàgbé láti lo ìgbàgbọ́ àti ìtẹramọ́ nwọn, nígbànã sì niàwọn iṣẹ́ ìyanu nã dáwọ́dúró, nwọn kò sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò nwọn; Nítorínã, nwọ́n ní ìdádúró nínú aginjù nã, tàbí pé nwọn kò rìn ní ọ̀nà tãrà, nwọ́n sì rí ìpọ́njú ebi àti òhùngbẹ, nítorí ìwàìrékọjá nwọn. Àti nísisìyí, ọmọ mi, èmi fẹ́ kí ìwọ mọ̀ pé àwọn ohun wọ̀nyí kò ṣaláì ní òjìji; nítorípé nígbàtí àwọn bàbá wa ya ọ̀lẹ láti kíyèsí atọ́nisọ́nà yĩ (ní báyĩ àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ ti ara) nwọn kò ṣe rere; bẹ̃ gẹ́gẹ́ sì ni àwọn ohun tí íṣe ti ẹ̀mí. Nítorí kíyèsĩ, ó rọrùn láti fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Krístì, èyítí yíò tọ́ka ọ̀nà tí ó gún sí àlãfíà pípé ayérayé sí ọ, bí o ṣe rí fún àwọn bàbá wa láti fetísílẹ̀ sí atọ́nisọ́nà yìi, èyítí yíò tọ́ka ọ̀nà tí ó gún sí ilẹ̀ ìlérí nã sí nwọn. Àti nísisìyí, èmi wí pé, njẹ́ kò ha sí irú rẹ̀ nínú ohun yĩ? Nítorípé gẹ́gẹ́bí afinimọ̀nà yĩ ní tọ́tọ́ ṣe mú àwọn bàbá wa, nípa títẹ̀lé ipa ọ̀nà rẹ̀, lọ sí ilẹ̀ ìlérí nã, bẹ̃ni awọn ọ̀rọ̀ Krístì, bí àwa bá tẹ̀lé ipa ọ̀nà wọn, yíò gbé wa kọjá àfonífojì ìbànújẹ́ yì, sínú ilẹ̀ ìlérí tí ó dára ju èyí nnì lọ. A! ọmọ mi, ma jẹ́ kí a ya ọ̀lẹ nítorí ìrọ̀rùn ọ̀nà nã; nítorípé bẹ̃ni ó rí fún àwọn bàbá wa; nítorípé bẹ̃ ni a ti ṣe pèsè rẹ̀ fún nwọn, pé tí nwọ́n bá lè wọ́ nwọn lè yè; bẹ̃ nã ni ó rí pẹ̀lú wa. A ti pèsè ọ̀nà nã sílẹ̀, bí àwa bá sì lè wò ó àwa yíò yè títí láéláé. Àti nísisìyí, ọmọ mi, rí i pé o tọ́jú àwọn ohun mímọ́ yĩ, bẹ̃ni, ríi pé ìwọ yí ojú rẹ sí Ọlọ́run kí o sì yè. Lọ sí ọ́dọ̀ àwọn ènìyàn yĩ kí o sì kéde ọ̀rọ̀ nã, kí o sì mã ronu jinlẹ. Ọmọ mi, ó dìgbóṣe. Àwọn òfin Álmà sí ọmọ rẹ̀ Ṣíblọ́nì. Èyítí a kọ sí orí 38. 38 Nwọ́n ṣe inúnibíni sí Ṣíblọ́nì nítorí ìwà òdodo rẹ̀—Ìgbàlà nbẹ nínú Krístì, ẹnití í ṣe ìyè àti ìmọ́lẹ̀ ayé—Kó gbogbo ìwà rẹ ní ìjánu. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Ọmọ mi, fi ètí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, nítorí èmi wí fún ọ, àní gẹ́gẹ́bí mo ti wí fún Hẹ́lámánì, pé níwọ̀n ìgbàtí ìwọ bá pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ìwọ yíò ṣe rere nínú ilẹ̀ nã; àti pé níwọ̀n ìgbàtí ìwọ kò bá pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ a ó ké ọ kúrò ní iwájú rẹ̀. Àti nísisìyí, ọmọ mi, ó dámi lójú pé èmi yíò ní ayọ̀ púpọ̀ lórí rẹ, nítorí ìdúró ṣinṣin rẹ àti ìsòtítọ́ rẹ sí Ọlọ́run; nítorípé gẹ́gẹ́bí ìwọ ṣe bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà èwe rẹ láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, gẹ́gẹ́bẹ̃ ni èmi ṣe ní írètí pé ìwọ yíò tẹ̀síwájú ní pípa àwọn òfin rẹ̀ mọ́; nítorípé ìbùkún ní fún ẹnití ó bá forítĩ dé òpin. Mo wí fún ọ́, ọmọ mi, pé èmi ti ní áyọ̀ púpọ̀ lórí rẹ síwájú, nítorí òtítọ́ rẹ àti ìgbọ́ran rẹ, àti ìpamọ́ra rẹ, àti ìfaradà rẹ lãrín àwọn ènìyàn tí íṣe ará Sórámù. Nítorí mo mọ̀ pé ìwọ wà nínú ìdè; bẹ̃ni, èmi sì tún mọ̀ pé nwọ́n sọ ọ́ ní òkúta nítorí ọ̀rọ̀ nã; ìwọ sì faradà gbogbo nkan wọ̀nyí pẹ̀lú sũrù nítorípéOlúwa wà pẹ̀lú rẹ; àti nísisìyí ìwọ mọ̀ pé Olúwa ni ó kó ọ yọ. Àti nísisìyí, ọmọ mi, Ṣíblọ́nì, èmi fẹ́ kí o rántí, pé níwọ̀n bí o bá gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni yíò kó ọ yọ nínú àwọn àdánwò rẹ, àti àwọn wàhálà rẹ, àti àwọn ìpọ́njú rẹ, a ó sì gbé ọ sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn. Nísisìyí, ọmọ mi, èmi kò fẹ́ kí o rò wípé fúnra mi ni mo mọ́ ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Ọlọ́run èyítí ó wà nínú mi ni o sọ àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀ fún mi; nítorípé bí kò bá ṣe pé a ti bí mi nípa ti Ọlọ́run, èmi kì bá ti mọ́ àwọn ohun wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Olúwa nínú ãnú nlá rẹ̀ rán ángẹ́lì rẹ̀ láti sọ fún mi pé èmi gbọ́dọ̀ da ìparun àwọn ènìyàn rẹ̀ dúró; bẹ̃ni, èmi sì ti rí ángẹ́lì ni ojúkojú, òun sì bá mi sọ̀rọ̀, ohun rẹ̀ sì dà bí àrá, ó sì mi gbogbo ilẹ̀. Ó sì ṣe tí èmi wà ní ipò ìrora àti ìbànújẹ́ ọkàn èyítí ó korò jùlọ fún ọ̀sán mẹta àti òru mẹ́ta; àti pé láìjẹ́wípé ó di ìgbà tí èmi kígbe pe Jésù Krístì Olúwa fún ãnú, ni èmi gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ mi. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi kígbe pẽ, mo sì rí àlãfíà gbà sínú ọkàn mi. Àti nísisìyí, ọmọ mi, èmi sọ eleyĩ fún ọ kí ìwọ kí ó lè kọ́ ọgbọ́n, kí ìwọ kí ó lè kọ́ ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ mi pé kò sí ọ̀nà míràn tàbí ipa tí a fi lè gbà ènìyàn là, àfi nínú àti nípasẹ̀ Krístì nikan. Kíyèsĩ, òun ni ìyè àti ìmọ́lẹ̀ ayé. Kíyèsĩ, òun ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti òdodo. Àti nísisìyí, bí ìwọ ti ṣe bẹ̀rẹ̀sí kọ́ni ní ọ̀rọ̀ nã, bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni èmi fẹ́ kí ó tẹ̀síwájú nínú kíkọ́ni; èmi sì fẹ́ kí o ní ìgbọ́ràn àti ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ohun gbogbo. Rí i pé ìwọ kò gbé ara rẹ sókè nínú ìgbéraga; bẹ̃ni, ríi pé ìwọ kò yangàn nínú ọgbọ́n ara rẹ, tàbí nínú agbára rẹ tí ó pọ̀. Lo ìgboyà, ṣùgbọ́n máṣe jẹ gàba léni lórí; àti pẹ̀lú pé kí ó ríi pé ìwọ kó ara rẹ ní ìjánu nínú ohun gbogbo, kí ìwọ bá lè kún fún ìfẹ́; ríi pé o yẹra fún ìwà ọ̀lẹ. Máṣe gbàdúrà bí àwọn ará Sórámù, nítorítí ìwọ ti ríi pé nwọn a máa gbàdúrà kí ènìyàn bá lè gbọ́ nwọn, kí nwọ́n sì yìn wọ́n fún ọgbọ́n nwọn. Máṣe sọ wípé: A! Ọlọ́run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé àwa dára ju àwọn arákùnrin wa; ṣùgbọ́n dípò èyí nnì sọ wípé: A! Olúwa, dáríjì mí ni ti àìpé mi, kí o sì rántí àwọn arákùnrin mi nínú ãnú—bẹ̃ni, fi àìpé rẹ han níwájú Ọlọ́run ni ìgbà gbogbo. Kí Olúwa kí ó sì bùkúnfún ọkàn rẹ, kí ó sì gbà ọ́ ní ọjọ́ ìkẹhìn sínú ìjọba rẹ̀, láti wà ní ipò àlãfíà. Nísisìyí máa lọ, ọmọ mi, kí o sì kọ́ àwọn ènìyàn yĩ ní ọ̀rọ̀ nã. Mã wà ní ipò ironujinlẹ. Ọmọ mi, ó dìgbóṣe. Àwọn òfin Álmà sí ọmọ rẹ̀ Kọ̀ríántọ́nì. Èyítí a kọ sí àwọn orí 39 títí ó fi dé 42 ní àkópọ̀. 39 Ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè jẹ́ ohun ìríra—Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Kòríántọ́nì dènà àwọn ará Sórámù láti gba ọ̀rọ̀ nã—Ìràpadà ti Krístì yíò gba àwọn olódodo tí ó tiwà ṣãjú rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo ní ohun díẹ̀ láti bá ọ sọ sí i ju èyítí mo bá arákùnrin rẹ sọ; nítorípé kíyèsĩ, njẹ́ ìwọ kò ha ṣe àkíyèsí ìdúró ṣinṣin arákùnrin rẹ, ìwà òdodo rẹ̀, àti àìsimi rẹ̀ ní pípa òfin Ọlọ́run mọ́ bí? Kíyèsĩ, njẹ́ òun kò ha ti fi ìlànà rere lélẹ̀ fún ọ bí? Nítorítí ìwọ kò kíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ mi gẹ́gẹ́bí ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe ṣe, lãrín àwọn ará Sórámù. Nísisìyí èyí ni ohun tí èmi ní ìlòdìsí ọ; ìwọ lọ yangàn nínú agbára rẹ àti ọgbọ́n rẹ. Èyí nìkan sì kọ́, ọmọ mi. Ìwọ ṣe ohun èyítí ó burú lójú mi; nítorítí ìwọ kọ iṣẹ́ ìránṣẹ́ sílẹ̀, tí o sì kọjá lọ sí ilẹ̀ Sírọ́nì, nínú ilẹ̀ àwọn ará Lámánì, tí o sì tọ obìnrin panṣágà nnì, Ísábẹ́lì lọ. Bẹ̃ni, ó mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn ṣáko; ṣùgbọ́n èyí kò tọ́ fún ọ láti ṣe, ọmọ mi. Ó yẹ kí ìwọ dojúkọ iṣẹ́ ìránṣẹ́ nã èyítí a fi lé ọ lọ́wọ́. Ìwọ kò ha mọ̀, ọmọ mi, pé àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ ohun ìríra níwájú Olúwa; bẹ̃ni, èyítí ó jẹ́ ohun ìríra tayọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀, àfi ìtàjẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ tàbí sísẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́? Nítorí kíyèsĩ, bí ìwọ bá sẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ lẹ́hìn tí ó ti ní ibùgbé nínú rẹ nígbàkan rí, tí ìwọ sì mọ̀ pé ò nsẹ́ ẹ, kíyèsĩ, èyĩ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì; bẹ̃ni, ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì pànìyàn láìkà ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀ Ọlọ́run sí, kò rọrùn fún un láti gba ìdáríjì; bẹ̃ni, mo wí fún ọ, ìwọ ọmọ mí, pé kò rọrùn fún un láti gba ìdáríjì. Àti nísisìyí, ọmọ mi, èmi fẹ́ nítorí Ọlọ́run, pé ìwọ ìbá má ti jẹ̀bi ìwà ẹ̀ṣẹ̀ nlá yĩ. Èmi kò ní tẹnumọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nã, láti ni ọkàn rẹ lára, bí kò bá jẹ́ fún ànfãní rẹ. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìwọ kò lè fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ pamọ́ kúrò níwájú Ọlọ́run; àti pé àfi bí ìwọ bá ronúpìwàdà, nwọn yíò dúró gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí takò ọ́ ní ọjọ́ ìkẹhìn. Nísisìyí ọmọ mi, èmi fẹ́ kí o ronúpìwàdà kí o sì kọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀, kí ìwọ má sì tẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ ojú rẹ mọ́, ṣùgbọ́n dá ara rẹ dúró nínú àwọn ohun wọ̀nyí gbogbo; nítorí àfi bí ìwọ bá ṣe eleyĩ, ìwọ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run rárá. A!, rántí, kí o sì sọọ́ di síṣe, kí o sì dá ara rẹ dúró nínú àwọn ohun wọ̀nyí. Èmi pàṣẹ fún ọ láti sọ ọ́ di síṣe láti bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ dámọ̀ràn nínú ohun tí ìwọ yíò bá ṣe; nítorí kíyèsĩ, ìwọ wà ní ìgbà èwe rẹ, ìwọ sì níláti gba ìtọ́sọ́nà lọ́wọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ. Kí ìwọ kí ó sì gba ìmọ̀ràn nwọn. Máṣe jẹ́ kí ohun asán tàbí aṣiwèrè kankan darí rẹ; máṣe jẹ́ kí èṣù tún darí ọkàn rẹ tọ àwọn panṣágà obìnrin nnì lọ. Kíyèsĩ, A! ọmọ mi, báwo ni àìṣedẽdé tí ìwọ mú bá àwọn ará Sórámù ti pọ̀ tó; nítorípé nígbàtí nwọ́n rí ìwà rẹ nwọn kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́. Àti nísisìyí Ẹ̀mí Olúwa sọ fún mi pé: Pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ láti ṣe rere, kí nwọn má bã darí ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sínú ìparun; nítorínã mo pàṣẹ fún ọ, ọmọ mi, nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run, pé kí o dáwọ́ dúró nínú ìwà àìṣedẽdé rẹ; Pé kí o yí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú gbogbo iyè, agbára àti ipa rẹ; pé kí ìwọ máṣe darí ọkànláti ṣe búburú mọ́; ṣùgbọ́n dípò èyí padà lọ bá nwọn, kí o sì jẹ́wọ́ àṣìṣe àti ìpanilára rẹ èyítí ìwọ ti ṣe. Má lépa ọrọ̀ tàbí àwọn ohun asán ayé yĩ; nítorí kíyèsĩ, ìwọ kò lè kó nwọn pẹ̀lú rẹ. Àti nísisìyí, ọmọ mi, èmi yíò sọ ohun díẹ̀ fún ọ nípa bíbọ̀ Krístì. Wọ́, mo wí fún ọ, pé òun ni ẹnití nbọ̀wá dájúdájú láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ; bẹ̃ni, ó nbọ̀wá láti kéde ìró ayọ̀ ti ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Àti nísisìyí, ọmọ mi, èyí ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ inú èyítí a pè ọ́ sì, láti kéde ìró ayọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yĩ, láti múra ọkàn nwọn sílẹ̀; tàbí pé kí ìgbàlà lè wá sí ọ́dọ̀ nwọn, kí nwọn lè múra ọkàn àwọn ọmọ nwọn sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nã ní àkokò tí yíò bá dé. Àti nísisìyí èmi yíò tu ọkàn rẹ lára díẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yĩ. Kíyèsĩ, ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún ọ ìdí rẹ tí ohun wọ̀nyí ṣe níláti jẹ́ mímọ̀ ṣãjú bíbọ̀ rẹ. Kíyèsĩ, mo wí fún ọ, njẹ́ ọkàn kan ní àkokò yĩ kò ha ní iye lórí lọ́wọ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́bí ọkàn kan yíò ṣe rí ní àkokò tí yíò bá dé bí? Njẹ́ kò ha tọ́ láti jẹ́ kí ìlànà ìràpadà nã di mímọ̀ sí àwọn ènìyàn yĩ àti sí àwọn ọmọ nwọn pẹ̀lú bí? Njẹ́ kò ha rọrùn ní àkokò yĩ nã fún Olúwa láti rán ángẹ́lì rẹ̀ láti kéde àwọn ìró ayọ̀ yĩ fún wa àti fún àwọn ọmọ wa, tàbí bí yíò ti ṣe lẹ́hìn ìgbà nã tí yíò bá dé bí? 40 Krístì mú àjĩnde gbogbo ènìyàn wá—Àwọn olódodo tí ó ti kú lọ sí párádísè nígbàtí àwọn ènìyàn búburú lọ sí òkùnkùn lóde láti dúró de ọjọ́ àjĩnde nwọn—Gbogbo ohun ni a ó ṣe ìdápadà rẹ̀ sí ipò nwọn ní dídára àti pípé nínú Àjĩnde nã. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyíọmọ mi èyí ni ohun tí ó kù tí mo fẹ́ bá ọ sọ; nítorípé mo wòye pé ọkàn rẹ pòrũru nípa àjĩnde òkú. Kíyèsĩ, mo wí fún ọ, pé kò sí àjĩnde—tàbí, kí èmi kí ó wí báyĩ, ni ọ̀nà míràn, pé ara ti ayé yĩ kò lè gbé ara àìkú wọ̀, ìdíbàjẹ́ yĩ kò lè gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀—àfi lẹ́hìn àkokò ti Krístì bá ti dé. Kíyèsĩ, òun ni ó mú àjĩnde òkú ṣẹ. Ṣùgbọ́n wọ́, ọmọ mi, àjĩnde nã kò ì tĩ yá. Nísisìyí, èmi fi ohun ìjìnlẹ̀ kan hàn ọ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ ni ó wà ní ìpamọ́, tí ẹnìkẹ́ni kò mọ̀ nwọ́n àfi Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi fi ohun kan hàn ọ́, èyítí èmi ti ṣe ìwãdí rẹ̀ tọkàntọkàn lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé kí èmi lè mọ̀—èyí ni nípa ti àjĩnde nã. Kíyèsĩ, àkokò kan wà ti a ti yàn tí gbogbo àwọn tí ó ti kú yíò jáde wa láti ipò-òkú nwọn. Nísisìyí nígbàtí àkokò yìi yíò dé, kò sí ẹnití ó mọ̣́; ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ̀ àkokò nã tí a ti yàn. Nísisìyí, bóyá ìgbà kanṣoṣo ni, tàbí ìgbà ẹ̃kẹjì, tàbí ìgbà ẹ̃kẹta, tí àwọn ènìyàn yíò jáde wa láti ipò-òkú, kò já mọ́ nkan; nítorípé Ọlọ́run mọ́ àwọn ohun wọ̀nyí gbogbo; ó sì tọ́ fún mi láti mọ̀ pé ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ ni èyí—pé àkokò kan wà tí a ti yàn tí gbogbo àwọn tí ó ti kú yíò jí dìde kúrò nínú ipò-òkú. Nísisìyí, o di dandan ki àlàfo kan wà lãrín àkókò ikú àti àkókò àjĩnde nã. Àti nísisìyí èmi bẽrè pé kíni yíò ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀mí ènìyàn lẹ́hìn tí ó bá kú títí di ìgbà tí a ti yàn fún àjĩnde nã? Nísisìyí bóyá ìgbà kanṣoṣo ni a yàn fún ènìyàn láti jí dìde, kò já mọ́ nkankan; nítorípé kĩ ṣe ìgbà kan nã ni gbogbo ènìyàn a máa kú, èyí kò sì já mọ́ nkankan; ohun gbogbo wọ̀nyí rí bí ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti pé àwọn ènìyàn nìkan ni nwọ́n a máa ṣírò ọjọ́ fún lílò ara nwọn. Nítorínã, àkokò kan wà tí a ti yàn fún ènìyàn pé nwọn yíò dìde kúrò nínú ipò-òkú; àti pé ìgbà kan sì wà lãrín àkokò ikú àti àjĩnde nã. Àti nísisìyí, nípa ti ìwọ̀n àkokò yĩ, kíni yíò ṣẹlẹ̀ sí ọkàn ọmọ ènìyàn ni ohun tí èmi ti wãdí tọkàn-tọkàn lọ́wọ́ Ọlọ́run láti mọ̀; èyí sì ni ohun tí èmi mọ̀ nípa rẹ̀. Nígbàtí àkokò nã yíò bá sì dé ti gbogbo ènìyàn yíò jí dìde, nígbànã ni nwọn yíò mọ̀ pé Ọlọ́run mọ́ gbogbo àkókò èyítí a ti yàn fún ọmọ ènìyàn. Nísisìyí, nípa ti ipò ti ọkàn nã yíò wà lẹ́hìn ikú títí di ìgbà àjĩnde—Kíyèsĩ, a ti fi hàn mí nípasẹ̀ ángẹ́lì kan, pé ẹ̀mí ènìyàn gbogbo, ní kété tí ó bá ti fi ara sílẹ̀, bẹ̃ni, ẹ̀mí ènìyàn gbogbo, bí nwọ́n jẹ́ rere tàbí nwọ́n jẹ́ búburú, a ó múu lọ sí ilẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run nã, ẹnití ó fún nwọn ní ìyè. Nígbànã ni yíò sì ṣe, tí a ó gba ẹ̀mí àwọn olódodo sí ipò ayọ̀, èyítí íṣe párádísè, ipò ìsinmi, ipò àlãfíà, níbití nwọn yíò ti sinmi kúrò nínú gbogbo lãlã nwọn, àti kúrò nínú gbogbo àníyàn, àti ìbànújẹ́. Nígbànã ni yíò sì ṣe, tí ẹ̀mí àwọn ènìyàn búburú, bẹ̃ni, àwọn tí nwọ́n burú—nítorí kíyèsĩ, nwọn kò ní ipa tàbí ìpín nínú Ẹ̀mí Olúwa; nítorí kíyèsĩ, nwọ́n yan iṣẹ́ búburú rọ́pò rere; nítorínã ẹ̀mí èṣù wọ inú wọn lọ, ó sì fi àgọ́-ara nwọn ṣe ilé—àwọn yìi ni a ó sì lé jáde sínú òkùnkùn òde; níbẹ̀ ni ẹkún, òun ìpohùnréré ẹkún, òun ìpáhìnkeke yíò wà, èyí sì rí bẹ̃ nítorí àìṣedẽdé nwọn, tí a darí wọn sí ìgbèkùn nípa eṣu. Báyĩ sì ni ipò tí ọkàn àwọn ènìyàn búburú wà, bẹ̃ni, nínú òkùnkùn, àti ipò ìbẹ̀rù, ìfòyà fún ìgbónà ìrunú ìbínú Ọlọ́run lórí nwọn; báyĩ ni nwọn ṣe wà ní ipò yĩ, àti àwọn olódodo pẹ̀lú ní párádísè, títí di àkokò àjĩnde nwọn. Nísisìyí, àwọn kan nbẹ tí nwọ́n ti ní ìmọ̀ pé ipò ayọ̀ àti ipò ìbànújẹ́ ọkàn nã, ṣãjú àjĩnde, jẹ́ àjĩnde àkọ́kọ́. Bẹ̃ni, èmi gbà pé a lè pẽ ní irú àjĩde kan, jíjí dìde ẹ̀mí tàbí ọkàn, àti mímú nwọn bọ́ sínú ayọ̀ tàbí ìbànújẹ́, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ ti a ti sọ. Sì kíyèsĩ, ẹ̀wẹ̀ a ti sọọ́, pé àjĩnde àkọ́kọ́ wà, àjĩnde gbogbo àwọn tí nwọ́n ti wà tẹ́lẹ̀ rí, tàbí tí nwọn ṣì wà, tàbí tí yíò wà, títí dé ìgbà àjĩnde Krístì kúrò nínú ipò-òkú. Nísisìyí, àwa kò lérò pé àjĩnde àkọ́kọ́ yĩ èyítí à nsọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ọ̀nà yí, lè jẹ́ àjínde ti àwọn ọkàn àti mímú nwọn wá sí ipò ayọ̀ tàbí ìbànújẹ́. Ìwọ kò lè rò pé ohun tí ó túmọ̀ sí ni èyí. Kíyèsĩ, mo wí fún ọ, Rárá; ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí ìtúndàpọ̀ ẹ̀mí pẹ̀lú ara, ti àwọn wọnnì láti ìgbà ayé Ádámù títí dé ìgbà àjĩnde Krístì. Nísisìyí i, bóyá ẹ̀mí àti ara àwọn wọnnì tí a ti sọ nípa nwọn yíò tún dàpọ̀ lẹ́sẹ̀kannã, tí àwọn ènìyàn búburú àti ti àwọn olódodo, èmi kò sọ bẹ̃; jẹ́ kí ó tẹ́ ọ lọ́run, pé mo wípé gbogbo nwọn jáde wá; tàbí kí a wípé, àjĩnde nwọn yíò wáyé ṣãjú àjĩnde àwọn tí ó kú lẹ́hìn àjĩnde Krístì. Nísisìyí, ọmọ mi, èmi kò wípé àjĩndé nwọn yíò wáyé ní àkokò ti àjĩnde Krístì; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi sọọ́ gẹ́gẹ́bí èrò ọkàn mi, pé ọkàn àti ara yíò tún dàpọ̀, ti àwọn olódodo, ní àkokò àjĩnde Krístì, àti ìgòkè re ọ̀run rẹ̀. Ṣùgbọ́n bóyá ní àkokò àjĩnde rẹ̀ ni yíò jẹ́, tàbí lẹ́hìn èyí, èmi kò wí bẹ̃; ṣùgbọ́n eleyĩ ni èmi wí pé àkokò kan yíò wà lẹ́hìn ikú àti àjĩnde ara, àti ipò ẹ̀mí nínú ayọ̀ tàbí ìbànújẹ́ títí di àkokò nã èyítí Ọlọ́run yàn tí àwọn tí ó ti kú yíò jáde wá, tí nwọ́n ó sì tún dàpọ̀, ní ọkàn àti ara, tí a ó sì mú nwọn dúró níwájú Ọlọ́run, tí a ó sì ṣe ìdájọ́ fún nwọn gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ nwọn. Bẹ̃ni, èyí ni ó mú ìmúpadàbọ̀sípò àwọn ohun wọnnì tí a ti sọ láti ẹnu àwọn wòlĩ wáyé. A ó dá ọkàn padà sínú ara, àti ara sínú ọkàn; bẹ̃ni, gbogbo ẹ̀yà ara òun orike ara ni a ó mú padà sínú ara tirẹ̀; bẹ̃ni, àní ẹyọ irun orí kan kì yíò sọnù; ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni a ó mú padà bọ̀ sí ipò dídára àti pípé rẹ̀. Àti nísisìyí, ọmọ mi, èyí ni ìmúpadàbọ̀sípò èyítí a ti sọ nípa rẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlĩ— Nígbànã ni àwọn olódodo yíò tàn jáde ní ìjọba Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ikú búburú yíò dé bá àwọn ènìyàn búburú; nítorítí nwọn yíò kú ní ti ohun tĩ ṣe ti òdodo; nítorípé nwọ́n jẹ́ aláìmọ́, kò sì sí ohun àìmọ́ kan tí ó lè jogún ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n a ó lé nwọn jáde, a ó sì mú nwọn jèrè iṣẹ́ ọwọ́ nwọn, tàbí iṣẹ́ nwọn, èyítí ó ti jẹ́ búburú; nwọn sì nmu gẹ̀dẹ̀gẹ̀dẹ̀ ãgo ìkorò. 41 Ní àjĩnde nã àwọn ènìyàn yíò jáde sínú ipò ayọ̀ aláìlópin tàbí ìbànújẹ́ aláìlópin—Ìwà búburú kò jẹ́ inú dídùn rí—Àwọn ènìyàn nipa ti ara wà láìní Ọlọ́run nínú ayé yĩ—Ní ìgbà ìmúpadàbọ̀sípò, olúkúlùkù yíò tún gba àwọn ìwà àti ìmọ̀ tí ó ti ní ní ìní nígbà ayé rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo ní ohun kan láti sọ nípa ìmúpadàbọ̀sípò nípa èyítí mo ti sọ ṣãjú; nítorípé kíyèsĩ, àwọn míràn ti yí ọ̀rọ̀ ìwé-mímọ́ po, nwọn sì ti kùnà púpọ̀ nítorínã. Èmi sì wòye pé ọkàn rẹ dãmú pẹ̀lú nípa ohun yĩ. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi yíò ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ. Mo wí fún ọ, ọmọ mi, pé ìlànà ìmúpadàbọ̀sípò nã wà ní ìbámu pẹ̀lú àìṣègbè Ọlọ́run; nítorípé ohun tí ó yẹ ni kí a mú ohun gbogbo padàbọ̀sípò nwọn dáradára. Kíyèsĩ, ó yẹ ó sì tọ́, ní ìbámu pẹ̀lú agbára àti àjĩnde Krístì, pé kí a mú ọkàn ènìyàn padàbọ̀sípò pẹ̀lú ara rẹ̀, àti pé kí a mú gbogbo ẹ̀yà ara padàbọ̀sípò pẹ̀lú ara rẹ̀. Ó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú àìṣègbè Ọlọ́run pé kí àwọn ènìyàn gba ìdájọ́ gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ ọwọ́ nwọn; bí iṣẹ́ ọwọ́ nwọn ní ayé yĩ bá sì jẹ́ rere, tí ìfẹ́-inú ọkàn nwọn bá sì jẹ́ rere, ní ọjọ́ ìkẹhìn, a ó sì mú nwọn padàbọ̀sípò sínú èyítí ó jẹ́ rere. Bí iṣẹ́ nwọn bá sì jẹ́ búburú, a ó ṣe ìmúpadàbọ̀sípò fún nwọn sí búburú. Nítorínã, ohun gbogbo ni a ó mú padàbọ̀sípò sí ipa nwọn bí ó ti yẹ, ohun gbogbo sí ẹ̀yà àdánidá rẹ̀—gbé ikú dìde sí àìkú, ìdibàjẹ́ sí àìdibàjẹ́—tí a ó gbé e dìde sí ayọ̀ tí kò lópin láti jogún ìjọba Ọlọ́run, tàbí sí ìbànújẹ́ tí kò lópin láti jogún ìjọba ti èṣù, ọ̀kan ní apá kan, ìkejì ní apá kejì— Èyítí a gbé dìde sínú ayọ̀ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ̀ fún ayọ̀, tàbí rere gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ̀ fún rere; àti èyí kejì sí búburú gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ̀ fún búburú; nítorípé gẹ́gẹ́bí ó ti ni ìfẹ́ fún ṣíṣe búburú ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, bẹ̃ nã ni yíò rí ẹ̀san búburú nígbàtí alẹ́ bá dé. Bákannã ní ó sì rí ni ọ̀nà kéjì. Bí òun bá ti ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì lépa òdodo títí di òpin ọjọ́ ayé rẹ̀, bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni yíò rí ẹ̀san sí ti òdodo. Àwọn yìi ni àwọn tí Olúwa ti ràpadà; bẹ̃ni àwọn yĩ ni àwọn tí a ti yọ jáde, tí a ti yọ kúrò nínú ìgbà àṣálẹ́ aláìlópin nnì; bẹ̃sì ni nwọn yíò dúró tàbí kí nwọn ṣubú; nítorí kíyèsĩ, onídàjọ́ ara nwọn ni nwọ́n jẹ́, bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú. Báyĩ, àṣẹ Ọlọ́run wà láìyípadà; nítorínã, a ti pèsè ọ̀nà nã sílẹ̀ pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ lè rìn nínú rẹ̀ kí a sì gbã là. Àti nísisìyí kíyèsĩ, ọmọ mi, máṣe dáwọ́lé ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ sí Ọlọ́run rẹ nípa ti àwọn ìlànà ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ mímọ́, èyítí ìwọ ti dáwọ́lé láti dẹ́ṣẹ̀ títí di àkokò yĩ. Máṣe rò wípé, nítorípé a ti sọ̀rọ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò, pé a ó mú ọ padàbọ̀sípò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ sínú ìdùnú. Kíyèsĩ, mo wí fún ọ, ìwà búburú kò jẹ́ inú dídùn rí. Àti nísisìyí, ọmọ mi, gbogbo ènìyàn tí ó bá wà ní ipò ẹni àdánidá ti ayé, tàbí kí nwípé, nínú ipò ara, wà nínú ipò ìkorò òrọ́ró àti nínú ìgbèkùn àìṣedẽdé; nwọ́n wà láìní Ọlọ́run nínú ayé yĩ, nwọ́n sì ti wà ní ìlòdìsí ìwà-bíỌlọ́run; nítorínã, wọ́n wà ní ipò tí ó lòdì sí ìwà inú dídùn. Àti nísisìyí kíyèsĩ, njẹ́ ìtumọ̀sí ọ̀rọ̀ nã tí à npè ní ìmúpadàbọ̀sípò ha í ṣe pé kí a mú ohun tí ó wà ní ipò àdánidá ara ti ayé kí a sì fi sí ipò ti kĩ ṣe àdánidá, tàbí pé kí a fi sí ipò tí ó tako ti àdánidá rẹ̀? A!, ọmọ mi, èyí kò rí bẹ̃; ṣùgbọ́n ìtumọ̀sí ọ̀rọ̀ nã tí à npè ní ìmúpadàbọ̀sípò ni pé kí a mú búburú fún èyí tí íṣe búburú, tàbí ti ara fún ti ara, tàbí ti èṣù fún ẹni ti èṣù—rere fún èyítí í ṣe rere; òdodo fún èyítí íṣe òdodo; ohun ti o tọ́ fún èyítí ó tọ́, ãnú fún èyítí íṣe ãnú. Nítorínã, ọmọ mi, ríi pé o jẹ́ alãnú sí àwọn arákùnrin rẹ; ṣe èyítí ó tọ́, ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì máa ṣe rere títí lọ; bí ìwọ bá sì ṣe gbogbo nkan wọ̀nyí ìgbànã ni ìwọ yíò gba èrè rẹ; bẹ̃ni, ìwọ yíò tún rí ìmúpadàbọ̀sípò ãnú gba; ìwọ yíò tún rí ìmúpadàbọ̀sípò àìṣègbè gbà; ìwọ yíò túnrí ìmúpadàbọ̀sípò ìdájọ́ gbà; ìwọ yìó tún rí ẹ̀san rere gbà padà. Nítorípé ohun èyítí ìwọ bá fi ránṣẹ́ síta yíò tún padà sọ́dọ̀ rẹ, tí yíò sì di ìmúpadàbọ̀sípò; nítorínã, ọ̀rọ̀ nã tí à npè ní ìmúpadàbọ̀sípò dá ẹlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi púpọ̀ síi, kò sì dáa láre rárá. 42 Ipò ara ìdibàjẹ́ jẹ́ ìgbà ìdánwò tí ó fún ènìyàn ní ànfãní láti ronúpìwàdà àti láti sin Ọlọ́run—Ìṣubú nnì mú ikú ti ara àti ti ẹ̀mí wá sí órí ọmọ aráyé—Ìràpadà wá nípa ìrònúpìwàdà—Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ó ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ayé—ãnú jẹ́ tí àwọn tí ó ronúpìwàdà—Gbogbo àwọn tí ó kù wà lábẹ́ àìṣègbè Ọlọ́run—Àánú wá nítorí Ètùtù nã—Àwọn tí nwọn bá ronúpìwàdà nítọ́tọ́ nìkan ni a ó gbàlà. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo wòye pé ohun kan tún kù tí ó nni ọkàn rẹ lára, èyítí kò yé ọ—èyítí íṣe nípa àìṣègbè Ọlọ́run ní ti ìfìyàjẹ ẹlẹ́ṣẹ̀; nítorí ìwọ tiraka láti ròo pé ìṣègbè ni kí a fi ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ipò ìbànújẹ́. Nísisìyí kíyèsĩ, ọmọ mi, èmi yíò la ohun yĩ yé ọ. Nítorí kíyèsĩ, lẹ́hìn tí Olúwa Ọlọ́run lé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì, láti máa ro ilẹ̀, nínú èyítí a ti mú nwọn jáde wá—bẹ̃ni, ó mú ọkùnrin nã jáde, ó sì fi sí ìhà apá ìlà-oòrùn ọgbà Édẹ́nì nã, àwọn kérúbímù, àti idà iná èyítí njù kãkiri, láti máa ṣọ́ igi ìyè nã— Nísisìyí, a ríi pé ènìyàn nã ti dàbí Ọlọ́run, tí ó sì mọ́ rere àti búburú; njẹ́ kí ó má bã na ọwọ́ rẹ̀, kí ó sì mú nínú èso igi ìyè nã pẹ̀lú, kí ó sì jẹ kí ó sì yè títí láé, Olúwa Ọlọ́run fi kérúbímù àti idà iná sí ibẹ̀, kí ó má lè jẹ nínú èso nã— Bẹ̃ni àwa sì ríi pé a fún ènìyàn ní àkokò kan láti ronúpìwàdà, bẹ̃ni, àkokò ìdánwò, àkokò láti ronúpìwàdà àti láti sin Ọlọ́run. Nítorí kíyèsĩ, bí Ádámù bá ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde lẹ́sẹ̀kannã, tí ó sì ti jẹ nínú igi ìyè nã, kì bá wà ní ãyè títí láé, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òun kò sì ní ní àkokò tí yíò ronúpìwàdà; bẹ̃ ni, àti pẹ̀lú pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kì bá sì di òfo, ìlànà ìgbàlà nlá nnì yíò sì di asán. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, a ti yàn án fún ènìyàn láti kú—nítorínã, bí a ti ṣe pín nwọn níyà kúrò lára igi ìyè nã, a níláti pín nwọn níyà kúrò lórí ilẹ̀ ayé—ènìyàn sì sọnù títí láé, bẹ̃ni, nwọn di ẹni-ìṣubú. Àti nísisìyí, ìwọ ríi nípasẹ̀ nkan yĩ pé a ké àwọn òbí wa àkọ́kọ́ kúrò ni ti ara àti ti ẹ̀mí níwájú Olúwa; àwa sì ríi bẹ̃ pé nwọ́n di ẹni ara nwọn láti ṣe gẹ́gẹ́bí èrò inú ọkàn nwọn. Nísisìyí kíyèsĩ, kò jẹ́ ohun tí ó tọ́ kí a gba ènìyàn lọ́wọ́ ikú ti ara yĩ, nítorípé ṣíṣe èyí yìó pa ìlànà ayọ̀ nlá nnì run. Nítorínã, nítorípé ẹ̀mí ènìyàn kò lè kú, tí ìṣubú nnì sì ti mú ikú ẹ̀mí àti ikú ara bá gbogbo ènìyàn pé a ti ké nwọn kúrò níwájú Olúwa, ó jẹ́ ohun tí ó tọ́ ní ṣíṣe pé kí a gba ènìyàn lọ́wọ́ ikú ẹ̀mí yĩ. Nítorínã, nítorípé nwọ́n ti di ti ara, ti ayé àti ti èṣù ni ti ìdánidá nwọn, ipò ìdánwò yĩsì jẹ́ ipò fún nwọn láti murasílẹ̀; ó sì jẹ́ ipò ìmúrasílẹ̀. Àti nísisìyí rántí, ọmọ mi, bí kò bá jẹ́ fún ti ìlànà ìràpadà nnì, (tí a bá pa á tì) ní kété tí nwọn bá ti kú, ẹ̀mí nwọn yíò wà ní ipò ìbànújẹ́, nítorípé a ó ké nwọn kúrò níwájú Olúwa. Àti nísisìyí, kò sí ọ̀nà tí a fi lè gba ènìyàn kúrò nínú ipò ìṣubú yĩ, èyítí ènìyàn tí mú wá sí órí ara rẹ̀ nítorí ìwà àìgbọràn ara rẹ̀; Nítorínã, ní ìbámu pẹ̀lú àìṣègbè, ìlàna ìràpadà nnì kò lè wáyé, àfi nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà ènìyàn ní ipò ìdánwò yĩ, bẹ̃ni, ipò ìmúrasílẹ̀ yí; nítorípé bíkòbáṣe fún ti àwọn ìlànà wọ̀nyí, ãnú kò lè já mọ́ nkankan, àfi kí ó pa iṣẹ́ àìṣègbè run. Báyĩ iṣẹ́ àìṣègbè kò ṣeé parun; bí ó bá sì rí bẹ̃, Ọlọ́run kò ní jẹ́ Ọlọ́run mọ́. Báyĩ ni àwa sì ríi pé gbogbo ènìyàn ti ṣubú, tí nwọ́n sì wà lábẹ́ ìdarí àìṣègbè; bẹ̃ni, àìṣègbè Ọlọ́run, èyítí ó fi nwọ́n sí ipò ìkékúrò níwájú rẹ̀ títí láé. Àti nísisìyí, ìlànà ãnú nnì kò lè wáyé àfi bí a bá ṣe ètùtù kan; nítorínã, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ó ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ayé láti mú ìlànà ãnú nnì wáyé, láti ṣe ìtánràn fún ẹ̀tọ́ àìṣègbè, kí Ọlọ́run lè jẹ́ Ọlọ́run pípé àti títọ́, àti Ọlọ́run alãnú pẹ̀lú. Nísisìyí, ìrònúpìwàdà kò lè dé fún ènìyàn láìsí ìfìyàjẹni, èyítí ó sì jẹ́ tí ayérayé gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ènìyàn ṣe yẹ kí ó rí, tí a ti soó ní ìtakò mọ́ ìlànà ayọ̀ nnì, èyítí í ṣe ti ayérayé pẹ̀lú gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ènìyàn ṣe wà títí ayérayé. Nísisìyí, báwo ni ènìyàn ó ṣe ronúpìwàdà bí kò bá ṣe pé ó ṣẹ̀? Báwo ni yíò ṣe ṣẹ̀ bí kò bá sí òfin? Báwo ni òfin ó ṣe wà bí kò bá sí ìfìyàjẹni? Nísisìyí, a ti so ìfìyàjẹni mọ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sì fún ni ní òfin títọ́, èyítí ó mú ẹ̀dùn ọkàn lórí ẹ̀ṣẹ̀ bá ènìyàn. Nísisìyí, bí a kò bá fún ni ní òfin—bí ènìyàn bá pànìyàn ó níláti kú—njẹ́ yíò ha bẹ̀rù pé òun yíò ku bí òun bá pànìyàn? Àti pẹ̀lú, bí kò bá sí òfin tí a fi fúnni tí ó tako ẹ̀ṣẹ̀, ènìyàn kò ní bẹ̀rù láti dẹ́ṣẹ̀. Bí kò bá sì sí òfin tí a fún ni, bí ènìyàn bá dẹ́ṣẹ̀, kíni àìṣègbè lè ṣe, tàbí ãnú ẹ̀wẹ̀, nítorítí nwọn kò ní àṣẹ lórí ẹ̀dá nã? Ṣùgbọ́n òfin wà tí a fúnni, àti ìfìyàjẹni tí ó rọ̀ mọ́ ọ, àti ìrònúpìwàdà tí a fi fún ni; èyítí ìrònúpìwàdà ati ãnu tẹ́wọ́gbà; láìjẹ́bẹ̃, àìṣègbè yíò de ẹ̀dá nã, yíò sì ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́bí òfin, òfin yíò sì fìyàjẹni; bíkòbájẹ́ bẹ̃, iṣẹ́ àìṣègbè yíò parun, Ọlọ́run kò sì ní jẹ́ Ọlọ́run mọ́. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò lè ṣàì jẹ́ Ọlọ́run, ãnú sì rọ̀gbà ká olùrònúpìwàdà, ãnú sì wà nítorí ètùtù nnì; ètùtù nã sì mú àjĩnde òkú wa; àjĩnde òkú sì mú àwọn ènìyàn padà bọ̀wá síwájú Ọlọ́run; bẹ̃ sì ni a mú ènìyàn padàbọ̀sípò níwájú rẹ̀, fún ìdájọ́ gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ nwọn, ní ìbámu pẹ̀lú òfin àti àìṣègbè. Nítorí kíyèsĩ, àìṣègbè a máa ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀, ãnú nã pẹ̀lú a máa rọ̀gbàká gbogbo èyítí íṣe tirẹ̀; báyĩ, kò sí ẹni nã àfi èyítí ó bá ronúpìwàdà nítọ́tọ́ ni a ó gbàlà. Kíni, ìwọ ha rò wípé ãnú lè ja àìṣègbè lólè bí? Mo wí fún ọ, Rárá; kò lè rí bẹ̃ bí ó ti wù kí ókéré tó. Bí ó bá rí bẹ̃, Ọlọ́run yíò ṣe aláì jẹ́ Ọlọ́run mọ́. Bẹ̃ sì ni Ọlọ́run ṣe mú ìlànà nlá rẹ̀ ayérayé wá, àwọn tí a ti pèsè sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Bẹ̃ sì ni ìgbàlà àti ìràpadà àwọn ènìyàn ṣe wáyé, àti ìparun òun ìbànújẹ́ nwọn pẹ̀lú. Nítorínã, A! ọmọ mi, ẹnìkẹ́ni tí ó bá fẹ́ wá lè wá kí ó sì mu nínú omi ìyè nã ní ọ̀fẹ́; ẹnìkẹ́ni tí kò bá sì wá òun nã ni a kò fi dandan mú láti wa; ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìkẹhìn a ó ṣe ìmúpadàbọ̀sípò fún un gẹ́gẹ́bí ìṣe rẹ̀. Bí òun bá ti ní ìfẹ́ láti ṣe búburú, tí òun kò sì ronúpìwàdà ní ọjọ́ ayé rẹ̀, kíyèsĩ, búburú ni a ó ṣe síi, ní ìbámu pẹ̀lú ìmúpadàbọ̀sípò Ọlọ́run. Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo fẹ́ kí o máṣe jẹ́ kí àwọn ohun wọ̀nyí da ọkàn rẹ lãmu mọ́, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nìkan da ọkàn rẹ̀ lãmu, pẹ̀lú ìdãmú nnì èyítí yíò mú ọ bọ́ sí ipò ìrònúpìwàdà. A! ọmọ mi, mo fẹ́ kí o ṣíwọ́ sísẹ́ àìṣègbè Ọlọ́run. Máṣe gbìyànjú dídá ara rẹ̀ láre bí ó ti wù kí ó mọ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, nípa sísẹ́ àìṣègbè Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ kí àìṣègbè Ọlọ́run, àti ãnú rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ sũrù rẹ̀ yí ọkàn rẹ̀ padà; kí ó sì jẹ́ kí ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ nínú eruku ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn. Àti nísisìyí, A! ọmọ mi, Ọlọ́run pè ọ́ láti wãsù ọ̀rọ̀ nã sí àwọn ènìyàn yĩ. Àti nísisìyí, ọmọ mi, má bá tirẹ lọ, kí ó sì kéde ọ̀rọ̀ nã pẹ̀lú òtítọ́ àti ní àìrékọjá, kí ìwọ kí ó lè mú àwọn ọkàn wá sí ìrònúpìwàdà, kí ìlànà ãnú nlá nnì lè gbà nwọ́n. Kí Ọlọ́run kí ó sì ṣeé fún ọ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ mi. Àmín. 43 Álmà àti àwọn ọmọ rẹ̀ wãsù ọ̀rọ̀ nã—Àwọn ará Sórámù àti àwọn ènìyàn Nífáì míràn tí ó yapa di àwọn ènìyàn Lámánì—Àwọn ará Lámánì dojúkọ àwọn ará Nífáì ní ogun—Mórónì ṣe ìgbáradì fún àwọn ará Nífáì pẹ̀lú ìhámọ́ra ìdábòbò-ara-ẹni—Olúwa fi ète àwọn ará Lámánì han Álmà—Àwọn ará Nífáì dábọ́ bò ilé, àwọn òmìnírá, àwọn ẹbí àti ẹ̀sìn nwọn— Àwọn ọmọ ogun Mórónì àti Léhì yí àwọn ará Lámánì kãkiri. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ọmọ Álmà kọjá lọ lãrín àwọn ènìyàn nã, láti kéde ọ̀rọ̀ nã fún nwọn. Álmà pẹ̀lú, fúnrarẹ̀, kò sì lè sinmi, òun nã sì jáde. Nísisìyí a kò ní sọ̀rọ̀ mọ́ nípa ìwãsù tí nwọ́n ṣe, àfi pé nwọ́n wãsù ọ̀rọ̀ nã, àti òtítọ́ nã, ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ òun ìfihàn; nwọ́n sì wãsù gẹ́gẹ́bí ti ẹgbẹ́ mímọ́ ti Ọlọ́run nípa èyítí a ti pè nwọ́n. Àti nísisìyí èmi sì padà sí órí ọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ogun lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì, ní ọdún kejìdínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́. Nítorí kíyèsĩ, ó ṣe tí àwọn ará Sórámù di àwọn ará Lámánì; nítorínã, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kejìdínlógún àwọn ará Nífáì ríi pé àwọn ará Lámánì mbọ̀wá láti kọlũ nwọ́n; nítorínã nwọ́n ṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun; bẹ̃ni, nwọ́n kó àwọn ọmọ ogun nwọn jọ sínú ilẹ̀ Jẹ́ṣónì. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì dé ní ẹgbẽgbẹ̀rún nwọn; nwọ́n sì wá sínú ilẹ̀ Ántíónọ́mù, tí íṣe ilẹ̀ àwọn ará Sórámù; ọkùnrin kan tí à npe orúkọ rẹ̀ ní Sẹrahẹ́múnà sì ni olórí nwọn. Àti nísisìyí, nítorípé àwọn ará Ámálẹ́kì ní ìwà búburú àti ìpànìyàn lọ́wọ́ ju àwọn ará Lámánì lọ, tìkàra nwọn, nítorínã, Sẹrahẹ́múnà yan àwọn olórí ọmọ ogun lé àwọn ará Lámánì lórí, gbogbo nwọn sì jẹ́ ará Ámálẹ́kì àti ará Sórámù. Nísisìyí ó ṣe eleyĩ kí ó lè pa ìkórira nwọn sí àwọn ará Nífáì mọ́, kí ó lè mú nwọn sí ábẹ́ àṣeyọrí ète rẹ̀. Nítorí kíyèsĩ, ète rẹ̀ ni pé kí ó rú àwọn ará Lámánì sókè ní ìbínú sí àwọn ará Nífáì; èyí ni ó ṣe láti lè fi ipá lo agbára nlá lórí nwọn, àti pẹ̀lú pé kí ó lè gba agbára lórí àwọn ará Nífáì nípa mímú nwọn sínú oko-ẹrú. Àti nísisìyí ète àwọn ará Nífáì ni láti dábọ́bò ilẹ̀ nwọn, àti ilé nwọn, àti àwọn ìyàwó nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn, láti pa nwọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn; àti pẹ̀lú pé kí nwọn ó lè pa ẹ̀tọ́ òun ànfãní nwọn mọ́, bẹ̃ni, àti òmìnira nwọn pẹ̀lú, pé kí nwọn ó lè sin Ọlọ́run gẹ́gẹ́bí nwọ́n ti fẹ́. Nítorítí nwọn mọ̀ pé bí àwọn bá subu sọ́wọ́ àwọn ará Lámánì, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá sin Ọlọ́run ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́, Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè, ni àwòn ará Lámánì yíò parun. Bẹ̃ni, nwọ́n sì mọ́ ọ̀pọ̀ ìkórira tí àwọn ará Lámánì ní fún àwọn arákùnrin nwọn, tĩ ṣe àwọn ènìyàn tí Kòṣe-Nífáì-Léhì, tí à npè ní àwọn ènìyàn Ámọ́nì—Tí nwọn kò sì ní gbé ohun ìjà-ogun, bẹ̃ni, nwọn ti dá májẹ̀mú, nwọn kò sì ní sẹ́ẹ—nítorínã, bí nwọn bá bọ́ sọ́wọ́ agbára àwọn ará Lámánì, a ó pa wọn run. Àwọn ará Nífáì kò sì fé kí nwọn pa nwọ́n run; nítorínã nwọ́n fún nwọn ní ilẹ̀ fún ìní nwọn. Àwọn ènìyàn Ámọ́nì sì fún àwọn ará Nífáì ní èyítí ó pọ̀ nínú ohun ìní nwọn láti ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ ogun nwọn; báyĩ sì ni ó di dandan pé kí àwọn ará Nífáì, nìkan, kọlũ àwọn ará Lámánì, tí nwọn íṣe àdàpọ̀ ìran Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì, àti àwọn ọmọ Íṣmáẹ́lì, àti gbogbo àwọn tí nwọ́n ti yípadà kúrò lára àwọn ará Nífáì, tí nwọn í ṣe ará Ámálẹ́kì àti àwọn ará Sórámù, àti àwọn ìran àwọn àlùfã Nóà. Nísisìyí àwọn ìran nã fẹ́rẹ̀ pọ̀ tó àwọn ará Nífáì; báyĩ sì ni ó rí tí àwọn ará Nífáì fi níláti bá àwọn arákùnrin nwọn jà dandan, àní títí dé ojú ìtàjẹ̀sílẹ̀. Ó sì ṣe bí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì sì ti kó ara nwọn jọ ní ilẹ̀ Ántíónọ́mù, kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì ti múrasílẹ̀ láti dojúkọ nwọn ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì. Nísisìyí, olórí àwọn ará Nífáì, tàbí pé ẹnití nwọn ti yàn láti jẹ́ ọ̀gágun lórí àwọn ará Nífáì—nísisìyí ọ̀gágun nã ṣe àkóso lórí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì—orúkọ rẹ̀ sì ni Mórónì; Mórónì sì ṣe àkóso, àti ìdarí gbogbo àwọn ogun nwọn. Ó sì jẹ́ ọmọ ogún ọdún àti mãrún nígbàtí a yàn án gẹ́gẹ́bí ọ̀gágunlórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì. Ó sì ṣe tí ó kọlũ àwọn ará Lámánì ní ibi ìhà ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, àwọn ènìyàn rẹ̀ sì di ìhámọ́ra ogun pẹ̀lú idà, àti pẹ̀lú ọrun, àti onírurú àwọn ohun ìjà ogun. Nígbàtí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì sì ríi pé àwọn ènìyàn Nífáì, tàbí pé Mórónì, ti ṣe ìmúrasílẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ìgbayà àti pẹ̀lú ìhámọ́ra tí nwọ́n fi bò apá nwọn, bẹ̃ni, àti asà láti dábọ́bò orí nwọn, nwọ́n sì wọ ẹ̀wù tí ó nípọn pẹ̀lú— Nísisìyí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Sẹrahẹ́múnà kò ṣe irú ìmúrasílẹ̀ báyĩ; idà nwọn àti símẹ́tà nwọn nìkan ni nwọ́n ní, ọrùn nwọn àti ọfà nwọn, òkúta nwọn àti kànnà-kànnà nwọn; nwọ́n sì wà ní ìhòhò, àfi fún ti awọ tí nwọ́n sán mọ́ ìbàdí nwọn; bẹ̃ni, gbogbo nwọn ni ó wà ní ìhòhò, àfi àwọn ará Sórámù, àti àwọn ará Ámálẹ́kì; Ṣùgbọ́n nwọn kò ṣe ìhámọ́ra pẹ̀lú igbaya-ogun, tàbí apata—nítorínã, nwọn kún fún ìbẹ̀rù àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì fún ti ìhámọ́ra nwọn, l’áìṣírò ti iye nwọn tí ó pọ̀ púpọ̀ ju ti àwọn ará Nífáì lọ. Kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe tí nwọn kò wá láti dojúkọ àwọn ará Nífáì ní ibi ìhà ilẹ̀ Jẹ́ṣónì; nítorínã nwọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ántíónọmù lọ sínú aginjù nã, nwọ́n sì rin ìrìn-àjò nwọn káakiri nínú aginjù nã, kọjá lọ sí ibi orísun odò Sídónì, kí nwọ́n lè wá sínú ilẹ̀ Mántì láti mú ilẹ̀ nã ní ìkógun; nítorítí nwọn kò lérò pé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì yíò mọ́ ibití àwọn ti lọ. Ṣùgbọ́n ó ṣe, ní kété tí nwọ́n ti kọjá lọ sínú aginjù, Mórónì rán àwọn amí lọ sínú aginjù láti ṣọ́ àgọ́ nwọn; àti Mórónì, pẹ̀lú, nítorípé ó mọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Álmà, rán àwọn ènìyàn kan sí i, pé kí ó bẽrè lọ́wọ́ Olúwa ibití àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì yíò lọ láti lè dábọ́bò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Álmà wá, tí Álmà sì wí fún àwọn oníṣẹ́ Mórónì, pé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì nrìn kãkiri nínú aginjù, kí nwọn ó lè kọjá sínú ilẹ̀ Mántì, kí nwọ́n lè bẹ̀rẹ̀sí dojú ìjà kọ àwọn apá ibití àwọn ènìyàn nã ti ṣe aláì lágbára tó bẹ̃. Àwọn oníṣẹ́ nã sì lọ láti jíṣẹ́ nã fún Mórónì. Nísisìyí lẹ́hìn tí Mórónì ti fi apá kan nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sílẹ̀ sí ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, ní ìfòyà pé apá kan nínú àwọn ará Lámánì lè wá lọ́nàkọnà sínú ilẹ̀ nã kí nwọ́n sì mú ìlú nã ní ìkógun, ó mú ìyókù àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, nwọ́n sì kọjá lọ sínú ilẹ̀ Mántì. Ó sì mú kí gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ nã kó ara nwọn jọ bá àwọn ará Lámánì jagun, láti dãbò bò ilẹ̀ nwọn àti orílẹ̀-èdè nwọn, ẹ̀tọ́ nwọn àti òmìnira nwọn; nítorínã nwọn ṣe ìmúrasílẹ̀ de ìgbà nã tí àwọn ará Lámánì yíò de. Ó sí ṣe tí Mórónì mú kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ farapamọ́ nínú àfonífojì tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ odò Sídónì, èyítí ó wà ní apá ìwọ oòrùn odò Sídónì, nínú aginjù nã. Mórónì sì fi àwọn alamí kãkiri ibẹ̀, kí òun lè mọ̀ ígbàtí àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì yíò bá dé. Àti nísisìyí, nítorípé Mórónì ti mọ́ ète àwọn ará Lámánì nã, pé ète nwọn ni láti pa àwọn arákùnrin nwọn run, tàbí pé kí nwọn ó mú nwọ́n sínú ìgbèkùn kí nwọn lè fi ìjọba lélẹ̀ fún ànfãní ara nwọn lórí gbogbo ilẹ̀ nã; Àti nítorípé òun mọ̀ pé ìfẹ́ kanṣoṣo tí àwọn ará Nífáì ní ni láti ṣe ìpamọ́ àwọn ilẹ̀ nwọn, àti òmìnira nwọn, àti ìjọ nwọn, nítorínã òun kò kã sí ẹ̀ṣẹ̀ láti dábò bò nwọ́n lọ́nà ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí; nítorínã, ó mọ̀ nípasẹ̀ àwọn alamí rẹ̀ ọ̀nà tí àwọn ará Lámánì yíò gbà. Nítorínã, ó pín àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ó sì mú apá kan nínú nwọn wá sínú àfonífojì nã, ó sì fi nwọn pamọ́ sí ìhà apá ìlà-oòrùn, àti ní apá gũsù òkè Ríplà; Àwọn tí ó kù ni ó sì fi pamọ́ sí àfonífojì ti ìwọ̀-oòrùn, ní apá ìwọ̀-oòrùn odò Sídónì, àti bẹ̃bẹ̃ títí fi dé ìhà agbègbè ìpẹ̀kun ilẹ̀ Mántì. Bí ó sì ti pín àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sí ibití ó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣetán láti dojúkọ nwọ́n. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì kọjá wá sí apá ìhà àríwá òkè nã, níbití díẹ̀ nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì farapamọ́ sí. Nígbàtí àwọn ará Lámánì sì ti kọjá òkè Ríplà, tí nwọn dé inú àfonífojì nã, tí nwọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀sí dá odò Sídónì kọjá, ẹgbẹ́ ọmọ ogun èyítí ó ti farapamọ́ sí apá gũsù òkè nã, tí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ íṣe Léhì sì jẹ́ olórí nwọn, ó sì darí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jáde wá ó sì yí àwọn ará Lámánì ká ní apá ìlà-oòrùn ní ẹ̀hìn nwọn. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì, nígbàtí nwọ́n rí àwọn ará Nífáì tí nwọ́n nbọ̀ láti ẹ̀hìn nwọn wá, nwọ́n yípadà nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Léhì jà. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa ara nwọn lápá méjẽjì, ṣùgbọ́n apá àwọn ará Lámánì ni ó ti burú jù, nítorítí wíwà ní ìhọ́hò nwọn mú kí nwọ́n fi ara gba ọgbẹ́ àwọn ará Nífáì nípasẹ̀ idà nwọn àti símẹ́tà nwọn, èyítí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo lílù rẹ̀ ni ó mú ikú wa. Ṣùgbọ́n ẹ̀wẹ̀, lãrín àwọn ará Nífáì enítere-èjìtere ni ènìyàn ṣubú nípasẹ̀ idà nwọn àti ìpàdánù ẹ̀jẹ̀, nítorípé nwọ́n dãbò bò àwọn ẹ̀yà ara nwọn tí ó ṣe pàtàkì, tàbí pé àwọn ẹ̀yà ara nwọn tí ó ṣe pàtàkì ni nwọ́n dãbò bò lọ́wọ́ lílù àwọn ará Lámánì, nípasẹ̀ àwo àyà nwọn, àti pẹ̀lú ìhámọ́ra tí nwọ́n fi bò apá nwọn, àti ìhámọ́ra àṣíborí nwọn; báyĩ sì ni ará Nífáì tẹ̀síwájú nínú pípa àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí ẹ̀rù bá àwọn ará Lámánì, nítorí ìparun nlá èyítí ó wà lãrín nwọn, àní tó bẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí sálọ sí apá ìhà odò Sídónì. Léhì àti àwọn ará rẹ̀ sì sá tẹ̀lé nwọ́n; Léhì sì lé nwọn sínú omi Sídónì, nwọ́n sì la omi Sídónì kọjá. Léhì sì dá àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ dúró ní etí bèbè odò Sídónì, pé kí nwọ́n má da kọjá. Ó sì ṣe tí Mórónì àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ bá àwọn ará Lámánì pàdé ní inú àfonífojì nã, ní òdì kejì odò Sídónì, nwọ́n sì npa nwọ́n. Àwọn ará Lámánì sì tún sá níwájú nwọn, sí apá ilẹ̀ Mántì; àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì sì tún bá nwọn pàdé. Nísisìyí ní báyĩ àwọn ará Lámánì jà kíkan-kíkan; bẹ̃ni, a kò ríi rí kí àwọn ará Lámánì ó jà pẹ̀lú agbára kíkan-kíkan àti ìgboyà bẹ̃, kò rí bẹ̃ pẹ̀lú láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Nwọ́n sì gba agbára láti ọwọ́ àwọn ará Sórámù àti àwọn ará Ámálẹ́kì, tí nwọn jẹ́ olórí ológun nwọn àti olùdarí nwọn, àti Sẹrahẹ́múnà, tĩ ṣe ọ̀gágun àti olùdarí àgbà nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n jà bí drágónì, tí a sì pa púpọ̀ nínú àwọn ará Nífáì nípasẹ̀ ọwọ́ nwọn, bẹ̃ni, nítorítí nwọ́n la púpọ̀ nínú àwọn ìhámọ́ra nwọn tí nwọ́n fi bò orí sí méjì, nwọ́n sì gún púpọ̀ nínú àwọn ìhámọ́ra àwo àyà nwọn, nwọ́n gé púpọ̀ nínú apá nwọn kúrò; báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì ṣe pa àwọn ará Nífáì nínú ìgbóná ìbínú nwọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ohun tí ó nta àwọn ará Nífáì jí dára ju ti àwọn ará Lámánì, nítorítí nwọn kò jà fún ìjọba tàbí àṣẹ, ṣùgbọ́n nwọn njà fún ilẹ̀ àti òmìnira nwọn, àwọn aya nwọn àti àwọn ọmọ nwọn, àti ohun gbogbo tí nwọ́n ní, bẹ̃ni, fún ìlànà ẹ̀sìn nwọn àti ìjọ-onígbàgbọ́ nwọn. Nwọ́n sì nṣe èyítí nwọ́n lérò wípé íṣe ojúṣe èyítí ó tọ́ sí Ọlọ́run nwọn; nítorítí Olúwa ti sọ fún nwọn, àti fún àwọn bàbá nwọn pẹ̀lú pé: Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kò jẹ̀bi ohun ìkọ̀sẹ̀ èkíní, tàbí èkejì, ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ fi ara nyín sílẹ̀ fún pípa nípasẹ̀ ọwọ́ àwọn ọ̀tá nyín. Àti pẹ̀lú, Olúwa ti wípé: Ẹ̀yin yíò dãbò bò àwọn ìdílé nyín àní títí dé ojú ìtàjẹ̀sílẹ̀. Nítorínã fún ìdí èyí ni àwọn ará Nífáì ṣe njà pẹ̀lú àwọn ará Lámánì, láti dãbò bò ara nwọn, àti àwọn ìdílé nwọn, àti ilẹ̀ nwọn, orílẹ̀-èdè nwọn, àti ẹ̀tọ́ nwọn, àti ẹ̀sìn nwọn. Ó sì ṣe, nígbàtí àwọn arákùnrin Mórónì rí ìgbóná àti ìrunú àwọn ará Lámánì, nwọ́n ṣetán láti dáwọ́dúró kí nwọ́n sì sálọ kúrò níwájú nwọn. Mórónì nã, nítorítí ó rí ohun tí nwọ́n fẹ́ ṣe, ó ránṣẹ́ ó sì kì nwọ́n láyà pẹ̀lú èrò wọ̀nyí—bẹ̃ni, èrò nípa ilẹ̀ nwọn, òmìnira nwọn, bẹ̃ni, ìtúsílẹ̀ nwọn kúrò nínú ìgbèkùn. Ó sì ṣe tí nwọ́n yí padà dojúkọ àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì jọ képe Olúwa Ọlọ́run nwọn ní ohun kan, fún òmìnira nwọn àti ìtúsílẹ̀ nwọn kúrò nínú ìgbèkùn. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí dojúkọ àwọn ará Lámánì pẹ̀lú agbára; àti pé ní wákàtí kannã tí nwọ́n ké pe Olúwa fún òmìnira nwọn, àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí sálọ kúrò níwájú nwọn; nwọ́n sì sá lọ àní sí odò Sídónì. Nísisìyí, àwọn ará Lámánì pọ̀ jù nwọ́n lọ, bẹ̃ni, kọjá ọ̀nà ìlọ́po méjì iye àwọn ará Nífáì; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n lé nwọn tó bẹ̃ tí nwọ́n fi kó ara nwọn jọ ní agbo kanṣoṣo nínú àfonífojì nã, ní etí bèbè ní ẹ̀gbẹ́ odò Sídónì. Nítorínã àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì yí nwọn ká, bẹ̃ni, àní ní ẹ̀gbẹ́ mèjèjì odò nã, nítorí kíyèsĩ, ní apá ìlà-oòrùn ni àwọn ènìyàn Léhì wà. Nítorínã nígbàtí Sẹrahẹ́múnà rí àwọn ènìyàn Léhì ní apá ìlà-oòrùn odò Sídónì, àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì ní apáìwọ̀-oòrùn odò Sídónì, pé àwọn ará Nífáì ti yí nwọn ká, ìpayà bá nwọn. Nísisìyí, nígbàtí Mórónì rí ìpayà nwọn, ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé kí nwọ́n dáwọ́ ìtàjẹ̀sílẹ̀ nwọn dúró. 44 Mórónì pàṣẹ fún àwọn ará Lámánì láti dá májẹ̀mú wíwà lálãfíà tàbí kí a pa nwọ́n run—Sẹrahẹ́múnà kọ àbá nã, ìjà nã sì tún bẹ̀rẹ̀—Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì ṣẹgun àwọn ará Lámánì. Ní ìwọ̀n ọdún 74 sí 73 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí nwọ́n dáwọ́dúró tí nwọ́n sì fà sẹ́hìn díẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ nwọn. Mórónì sì wí fún Sẹrahẹ́múnà: Kíyèsĩ, Sẹrahẹ́múnà, pé àwa kò ní ìfẹ́ láti jẹ́ ẹni tíi tàjẹ̀ ènìyàn sílẹ̀. Ẹ̀yin mọ̀ pé ẹ̀yin ti bọ́ sí wa lọ́wọ́, síbẹ̀ àwa kò ní ìfẹ́ láti pa nyín. Kíyèsĩ, àwa kò jáde wá láti dojú ìjà kọ nyín láti ta ẹ̀jẹ̀ nyín sílẹ̀ láti pàṣẹ lórí nyín; bẹ̃ sì ni àwa kò ní ìfẹ́ láti mú ẹnìkẹ́ni ní ìgbèkùn. Ṣùgbọ́n eleyĩ ni ìdí tí ẹ̀yin fi jáde wá dojú kọ wá; bẹ̃ni, ẹ̀yin sì nbínú sí wa nítorí ẹ̀sìn wa. Ṣùgbọ́n nísisìyí, ìwọ ríi pé Olúwa wà pẹ̀lú wa; ìwọ sì ríi pé ó ti fi yín lé wa lọ́wọ́. Àti nísisìyí èmi fẹ́ kí ó yé ọ pé a ṣe eleyĩ fún wa nítorí ti ẹ̀sìn wa àti ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Krístì. Àti nísisìyí ìwọ ríi pé ẹ̀yìn kò lè pa ìgbàgbọ́ wa yĩ run. Nísisìyí ìwọ ríi pé eleyĩ ni í ṣe ìgbàgbọ́ òtítọ́ ti Ọlọ́run; bẹ̃ni, ìwọ ríi pé Ọlọ́run yíò ṣe àtìlẹhìn, yíò sì ṣe ìtọ́jú, yíò sì pa wá mọ́, ní ìwọ̀n ìgbà tí àwa bá jẹ́ olódodo síi, àti sí ìgbàgbọ́ wa, àti ẹ̀sìn wa; láé ni Olúwa kò sì ní jẹ́ kí ẹnìkẹ́ni ó pa wá run àfi tí àwa bá ṣubú sínú ìrékọjá tí àwa sì sẹ́ ìgbàgbọ́ wa. Àti nísisìyí, Sẹrahẹ́múnà, mo pàṣẹ fún ọ, ní orúkọ Ọlọ́run ẹnití ó lágbára jùlọ, ẹnití ó ti fi agbára fún apá wa tí àwa sì ti lágbára jù nyín lọ, nípa ti ìgbàgbọ́ wa, nípa ti ẹ̀sìn wa, àti nípa ìlànà ìsìn wa àti nípa ti ìjọ wa, àti nípa ti ìtọ́jú tí í ṣe ohun ọ̀wọ̀ tí a níláti ṣe fún àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa, nípa ti ẹ̀tọ́ nnì èyítí ó so wá mọ́ ilẹ̀ wa àti orílẹ̀-èdè wa; bẹ̃ni, àti pẹ̀lú nípa ìpamọ́ ọ̀rọ̀ mímọ́ Ọlọ́run, èyítí a jẹ ní gbèsè fún gbogbo inúdídùn wa; àti nípa ohun gbogbo tí ó ṣọ̀wọ́n fún wa jùlọ— Bẹ̃ni, èyí kĩ sĩ ṣe gbogbo rẹ̀; mo pàṣẹ fún nyín nípa ti gbogbo ìfẹ́ tí ẹ̀yin ní fún ìyè, pé kí ẹ kó àwọn ohun ìjà nyín fún wa, àwa kò sì ní lépa láti ta ẹ̀jẹ nyín sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yíò dá ẹ̀mí nyín sí, bí ẹ̀yin yíò bá máa bá tiyín lọ tí ẹ kò sì ní wá mọ́ láti ja ogun pẹ̀lú wa. Àti nísisìyí, bí ẹ̀yin kò bá ṣe èyí, ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti bọ́ sí wa lọ́wọ́, èmi yíò sì pàṣẹ fún àwọn ará mi pé kí nwọ́n ṣá nyín lọ́gbẹ́ ikú lára nyín kí ẹ̀yin ó sì di aláìsí; nígbànã ni a ó sì rí ẹnití yíò lágbára lórí àwọn ènìyàn yĩ; bẹ̃ni, a ó rí ẹnití a ó mú ní ìgbèkùn. Àti nísisìyí ó sì ṣe pé nígbàtí Sẹrahẹ́múnà ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó jáde tí ó sì kó idà rẹ̀ sílẹ̀ àti símẹ́tà rẹ̀, àti ọfà rẹ̀ léọwọ́ Mórónì, ó sì wí fún un pé: Kíyèsĩ, àwọn ohun ìjà ogun wa nìyí; àwa yíò kó nwọn lé ọ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n àwa kì yíò gbà láti bá ọ dá májẹ̀mú, èyítí àwa mọ̀ pé àwa kì yíò pa mọ́, àti àwọn ọmọ wa pẹ̀lú; ṣùgbọ́n ẹ kó àwọn ohun ìjà ogun wa, kí ẹ sì jẹ́ kí àwa ó kọjá lọ sínú aginjù; láìjẹ́bẹ̃ àwa yíò kó àwọn idà wa, àwa ó sì parẹ́ tàbí kí a ṣẹ́gun. Ẹ kíyèsĩ, àwa kì í ṣe ìgbàgbọ́ kan nã pẹ̀lú nyín; àwa kò gbàgbọ́ pé Ọlọ́run ni ó fi wá lé nyín lọ́wọ́; ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé ọgbọ́n àrekérekè nyín ni ó pa nyín mọ́ kúrò lọ́wọ́ idà wa. Ẹ kíyèsĩ, àwọn asà ìgbayà yín àti àwọn asà nyín ni ó pa nyín mọ́. Àti nísisìyín ígbàtí Sẹrahẹ́múnà sì ti parí sísọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Mórónì dá idà àti àwọn ohun-ìjà ogun, tí ó ti gbà, padà fún Sẹrahẹ́múnà, tí ó sì wípé: Kíyèsĩ, a dá ogun nã dúró. Nísisìyí, èmi kò lè yí ọ̀rọ̀ tí èmi ti sọ padà, nítorínã bí Olúwa ti nbẹ, ẹ̀yin kò ní lọ kúrò afi bí ẹ̀yin ó bá lọ kúrò pẹ̀lú ìbúra pé ẹ̀yin kò ní tún padà wá kọlũ wá láti bá wa jagun. Nísisìyí nítorítí ẹ̀yin wà lọ́wọ́ wa a ó ta ẹ̀jẹ̀ nyín sílẹ̀, tàbí kí ẹ̀yin ó jọ̀wọ́ ara nyín sílẹ̀ sí àwọn àbá tí èmi ti mú wá. Àti nísisìyí nígbàtí Mórónì sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Sẹrahẹ́múnà kó idà rẹ̀, ó sì bínú sí Mórónì, ó sì súré síwájú pé kí òun lè pa Mórónì; ṣùgbọ́n bí ó ti gbé idà rẹ̀ sókè, kíyèsĩ, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun Mórónì bẹ̃ àní lulẹ̀, ó sì dá ní ẹ̀gbẹ́ ẽkù rẹ̀; ó sì bẹ Sẹrahẹ́múnà pẹ̀lú tí ó fi ṣí awọ orí rẹ̀ bó tí ó sì bọ́ sílẹ̀. Sẹrahẹ́múnà sì yẹra kúrò lọ́dọ̀ nwọn bọ́ sí ãrin àwọn ọmọ ogun tirẹ̀. Ó sì tún ṣe tí ọmọ ogun nnì èyítí ó wà nítòsí, ẹnití ó ṣí awọ orí Sẹrahẹ́múnà bọ́, mú awọ orí nã kúrò nílẹ̀ ní ibi irun orí, ó sì gbé e lé ṣónṣó ẹnu idà rẹ̀, ó sì nã sí nwọn, tí ó sì sọ fún nwọn ní ohun rara pé: Àní gẹ́gẹ́bí awọ orí yĩ ṣe bọ́ lélẹ̀, èyítí í ṣe awọ orí olórí nyín, bẹ̃ni a ó ṣe ké nyín lulẹ̀ àfi bí ẹ̀yin bá kó àwọn ohun ìjà ogun nyín lélẹ̀ tí ẹ sì lọ kúrò pẹ̀lú májẹ̀mú wíwà lálãfíà. Nísisìyí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà, nígbàtí nwọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí nwọ́n sì rí awọ orí nã èyítí ó wà lórí idà, ẹ̀rù bá wọ́n; ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó sì jáde tí nwọ́n sì ju àwọn ohun ìjà ogun nwọn sílẹ̀ ní ibi ẹsẹ̀ Mórónì, tí nwọ́n sì dá májẹ̀mú wíwà lálãfíà. Gbogbo àwọn tí ó sì dá májẹ̀mú ni nwọ́n gbà kí nwọn lọ kúrò sínú aginjù. Nísisìyí ó sì ṣe tí Sẹrahẹ́múnà bínú gidigidi, tí ó sì rú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ó kù sókè sí ìbínú, láti bá àwọn ará Nífáì jà nínú agbára tí ó pọ̀ síi. Àti nísisìyí Mórónì bínú, nítorí oríkunkun àwọn ará Lámánì; nítorínã ó pàṣẹ pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀ kọlũ nwọ́n kí nwọ́n sì pa nwọ́n. O sì ṣe tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n; bẹ̃ni, àwọn ará Lámánì sì jà pẹ̀lú idà nwọn àti agbára nwọn. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìhọ́hò ara nwọn àti orí nwọn tí nwọn kò dãbò bò fi ara gba idà mímú àwọn ara Nífáì; bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, a gún nwọn a sì ṣá nwọn, bẹ̃ni, nwọ́n sì ṣubú kánkán lọ́wọ́ idààwọn ará Nífáì; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gbá nwọn kúrò, àní gẹ́gẹ́bí ọmọ ogun Mórónì nnì ti sọtẹ́lẹ̀. Nísisìyí, nígbàtí Sẹrahẹ́múnà rí i pé a ti fẹ́rẹ̀ pa gbogbo nwọn run tán, ó kígbe rara sí Mórónì, ó sì ṣe ìlérí pé òun yíò dá májẹ̀mú àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú nwọn, bí nwọ́n ó bá da ẹ̀mí àwọn tí ó kù sí, pé nwọn kò ní jáde wá bá nwọn jagun mọ́ láé. Ó sì ṣe tí Mórónì mú kí pípa nwọn tún dá dúró lãrín àwọn ènìyàn nã. O sì gba àwọn ohunìjà ogun lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì; lẹ́hìn tí nwọ́n sì ti bã dá májẹ̀mú wíwà lálãfíà nwọn jẹ́ kí nwọ́n lọ kúrò sínú aginjù. Nísisìyí iye àwọn tí ó kù nínú nwọn kò lónkà nítorípé iye nã pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀; bẹ̃ni, iye àwọn tí ó kú nínú nwọn pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nínú àwọn ará Nífáì àti nínú àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí nwọ́n ju àwọn òkú nwọn sínú omi odò Sídónì, ó sì gbé nwọn ṣàn lọ sínú ìsàlẹ̀ òkun. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, tàbí pé ti Mórónì, padà nwọ́n sì dé ilé nwọn àti ilẹ̀ nwọn. Báyĩ sì ni ọdún kejìdínlógún ti ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin. Báyĩ sì ni àkọsílẹ̀ fún ìrántí ti Álmà ṣe, èyítí ó kọ lé orí àwọn àwo ti Nífáì. Ìṣe àwọn ènìyàn Nífáì, àti ogun àti ìyapa nwọn, ní ìgbà ayé Hẹ́lámánì, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ti Hẹ́lámánì, èyítí ó ṣe ní ìgbà ayé rẹ̀. Èyítí a kọ sí àwọn orí 45 títí ó fi dé 62 ní àkópọ̀. 45 Hẹ́lámánì gba àwọn ọ̀rọ̀ Álmà gbọ́—Álmà ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun àwọn ará Nífáì—Ó súre fún, ó sì fi ilẹ̀ nã bú—Ó lè jẹ́ pé Ẹ̀mí ni ó mú Álmà lọ sí ókè ọ̀run, àní bí ti Mósè—Ìyapa gbilẹ̀ nínú ìjọ-onígbàgbọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 73 kí a tó bí Olúwa wa. Kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn Nífáì yọ̀ púpọ̀púpọ̀, nítorípé Olúwa tún ti gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn; nítorínã nwọn fi ọpẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n sì gba ãwẹ̀ púpọ̀, nwọ́n sì gbàdúrà púpọ̀, nwọ́n sì sin Ọlọ́run pẹ̀lú ayọ̀ nlá tí ó pọ̀ púpọ̀. Ó sì ṣe ní ọdún kọkàndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, tí Álmà tọ ọmọ rẹ̀ Hẹ́lámánì wá, ó sì wí fún un: Ìwọ ha gba àwọn ọ̀rọ̀ èyítí èmi bá ọ sọ gbọ́ nípa àwọn àkọsílẹ̀ nnì èyítí a ti pamọ́ bí? Hẹ́lámánì sì wí fún un: Bẹ̃ni, èmi gbàgbọ́. Álmà sì tún wípé: Ìwọ ha gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ẹnití nbọ̀wá bí? Ó sì wípé: Bẹ̃ni, èmi gba gbogbo ọ̀rọ̀ èyítí ìwọ sọ gbọ́. Álmà sì tún wí fún un: Njẹ́ ìwọ yíò pa àwọn òfin mi mọ́ bí? Òun sì wípé: Bẹ̃ni, èmi yíò pa àwọn òfin rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi. Nígbànã ni Álmà wí fún un: Ìbùkún ni fún ọ; Olúwa yíò sì ṣe rere fún ọ ní ilẹ̀ yí. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, mo ní ohun kan tí èmi yíò ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún ọ; ṣùgbọ́n ohun nã tí èmi yíò ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún ọ ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọọ́ di mímọ̀; bẹ̃ni, ohun nã tí èmi yíò ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún ọ kò gbọ́dọ̀ di mímọ̀, àní títí di ìgbà tí ìsọtẹ́lẹ̀ nã yíò di mímú ṣẹ; nítorínã kọ àwọn ọ̀rọ̀ èyítí èmi yíò sọ sílẹ̀. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ nã: Kíyèsĩ, mo wòye pé àwọn ènìyàn yĩ pãpã, àwọn ará Nífáì, gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ìfihàn èyítí nbẹ nínú mi, ní irínwó ọdún sí ìgbà tí Jésù Krístì yíò fi ara rẹ̀ hàn nwọ́n, yíò rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́. Bẹ̃ni, nígbànã ni nwọn yíò sì rí ogun àti àjàkálẹ̀ àrùn, bẹ̃ni, ìyàn àti ìtàjẹ̀sílẹ̀, àní títí àwọn ènìyàn Nífáì yíò di aláìsí— Bẹ̃ní, èyí yíò sì rí bẹ̃ nítorítí nwọn ó rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ nwọn ó sì ṣubú sínú àwọn iṣẹ́ òkùnkùn, àti ìfẹ́kúfẹ, àti onírurú irú àìṣedẽdé gbogbo; bẹ̃ni, mo wí fún ọ, pé nítorítí nwọn yíò ṣẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀ ńlá àti ìmọ̀, bẹ̃ni, mo wí fún ọ, pé láti ìgbà nã lọ, àní ìran kẹrin kò ní kọjá lọ tí àìṣedẽdé nla yĩ yíò fi dé. Nígbàtí ọjọ́ nlá nã yíò sì dé, kíyèsĩ, àkókò nã dé kánkán tí àwọn tí nbẹ nísisìyí, tàbí irú-ọmọ àwọn t í a kà mọ́ àwọn ènìyàn Nífáì lọ́wọ́lọ́wọ́ báyĩ, kò ní jẹ́ kíkà mọ́ àwọn ènìyàn Nífáì mọ́. Ṣùgbọ́n ẹnìkẹ́ni tí ó bá ṣẹ́kù, tí a kò sì parun ní ọjọ́ nlá nnì èyítí ó ní ẹ̀rù, ni a ó kàmọ́ àwọn ará Lámánì, nwọn ó sì dàbí nwọn, gbogbo nwọn, àfi àwọn díẹ̀ tí a ó pè ní ọmọ-ẹ̀hìn Olúwa; àwọn sì ni àwọn ará Lámánì yíò lé àní títí nwọn yíò fi di aláìsí. Àti nísisìyí nítorí àìṣedẽdé, ìsọtẹ́lẹ̀ yĩ yíò sì di mímúṣẹ. Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí Álmà ti sọ àwọn ohun wọ̀nyí fún Hẹ́lámánì, ni ó súre fún un, àti fún àwọn ọmọ rẹ̀ yókù; ó sì súre fún ayé nítorí ti àwọn olódodo. Ó sì wípé: Báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí—Ìfibú ni ilẹ̀ nã, bẹ̃ni, ilẹ̀ yìi, sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, ède, àti ènìyàn, sí ìparun, tí nwọn nṣe búburú, nígbàtí nwọ́n bá gbó tán; bí èmi sì ti wí bẹ̃ ni yíò rí; nítorítí èyí ni ìfibú àti ìbùkún Ọlọ́run lórí ilẹ̀ nã, nítorítí Olúwa kò lè bojúwò ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ìyọ́nú rárá bí ó ti lè wù kí ó mọ. Àti nísisìyí, nígbàtí Álmà ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó sùre fún ìjọ-onígbàgbọ́ nã, bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí nwọn yíò dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ láti ìgbà nã lọ. Nígbàtí Álmà sì ṣe eleyĩ tán ó jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, bí èyítí yíò lọ sínú ilẹ̀ Mẹ́lẹ́kì. O sì ṣe tí a kò gbọ́ nípa rẹ̀ mọ́; nípa ti ikú tàbí sísin rẹ̀ a kò mọ̀ nípa rẹ̀. Kíyèsĩ, àwa mọ́ eleyĩ, pé olódodo ènìyàn ni í ṣe; ìhín nã sì tàn ká lãrín gbogbo àwọn ènìyàn ìjọ-onígbàgbọ́ pé Ẹ̀mí ni ó mú u lọ sókè ọ̀run, tàbí pé ọwọ́ Olúwa ni ó gbée sin, àní bí ti Mósè. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àwọn ìwé mímọ́ sọ pé Olúwa gba Mósè sọ́dọ̀ ara rẹ̀; àwa sì ropé ó ti gba Álmà pẹ̀lú nínú ẹ̀mí, sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀; nítorínã, fún ìdí èyí, a kò mọ́ ohunkóhun nípa ikú àti sísìn rẹ̀. Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kọkàndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, tí Hẹ́lámánì kọjá lọ sí ãrín àwọn ènìyàn nã láti kéde ọ̀rọ̀ nã fún nwọn. Nítorí ẹ kíyèsĩ, nítorí ìjàogun nwọn pẹ̀lú àwọn ará Lámánì àti àwọn ìyapa kékèké tí ó pọ̀ àti àwọn ìrúkèrúdò tí ó ti wà lãrín àwọn ènìyàn nã, ó jẹ́ ohun tí ó tọ́ pé kí a kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lãrín nwọn, bẹ̃ni, àti pé kí a ṣe ìlànà nínú ìjọ nã. Nítorínã, Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ láti tún dá ìjọ onígbàgbọ́ nã sílẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ nã, bẹ̃ni, nínú gbogbo àwọn ìlú nlá jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã èyítí àwọn ènìyàn Nífáì ti ṣe ìjogún nwọn. O sì ṣe tí nwọn sì yan àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã, lé gbogbo àwọn ìjọ nã lórí. Àti nísisìyí ni ó sì ṣe lẹ́hìn tí Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ti yan àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni lé orí àwọn ìjọ nã ìyapa bẹ́ sílẹ̀ lãrín nwọn, tí nwọn kò sì ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ mọ́; Ṣùgbọ́n nwọ́n di onigbéraga, nítorítí nwọ́n ṣe ìgbéraga nínú ọkàn nwọn, nítorí ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ nwọn; nítorínã nwọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ lójú ara nwọn, tí nwọn kò sì ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ nwọn mọ́, láti máa wà ní ìdúróṣinṣin níwájú Ọlọ́run. 46 Amalikíà dìtẹ̀ láti di ọba—Mórónì gbé àsíá òmìnira sókè—Ó kó àwọn ènìyàn nã jọ láti dãbò bò ẹ̀sìn nwọn—Àwọn tí ó gbàgbọ́ nítọ́tọ́ ni a pè ní Onígbàgbọ́—Ọlọ́run yíò pa nínú ìyókù àwọn àtẹ̀lé Jósẹ́fù mọ́—Amalikíà pẹ̀lú àwọn olùyapa sálọ sí ilẹ̀ Nífáì—Àwọn tí ó kọ̀ láti ti jíjà fún-òmìnira nã lẹ́hìn ni nwọ́n pa. Ní ìwọ̀n ọdún 73 sí 72 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí gbogbo àwọn tí kò ní etí ìgbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kó ara nwọn jọ ní ìtakò sí àwọn ará nwọn. Àti nísisìyí kíyèsĩ, nwọ́n bínú gidigidi, tó bẹ̃ tí nwọ́n pinnu láti pa nwọ́n. Nísisìyí olórí àwọn tí nbínú sí àwọn arákùnrin nwọn ni ọkùnrin títóbi àti alágbára kan; orúkọ rẹ̀ sì ni Amalikíà. Amalikíà sì fẹ́ láti jẹ ọba; àwọn ènìyàn tí nwọn nbínú nã sì fẹ́ kí ó jẹ́ ọba nwọn; púpọ̀ nínú nwọn ni nwọ́n sì jẹ́ onídàjọ́ ní ilẹ̀ nã, nwọ́n sì nwá agbára. Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn Amalikíà sì darí nwọn, pé bí nwọ́n bá ti òun lẹ́hìn tí nwọ́n sì fi òun ṣe ọba nwọn pé òun yíò fi nwọ́n ṣe olórí lórí àwọn ènìyàn nã. Báyĩ sì ni Amalikíà darí nwọn lọ sí tí ìyapa, l’áìṣírò fún ìwãsù Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, bẹ̃ni, l’áìṣírò fún ìtọ́jú nlá tí nwọn fún ìjọ-onígbàgbọ́ nã, nítorí olórí àlùfã ni nwọn í ṣe lórí ìjọ nã. Púpọ̀ ni ó sì wà nínú ìjọ nã tí nwọ́n gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn Amalikíà gbọ́, nítorínã nwọ́n yapa kúrò nínú ìjọ onígbàgbọ́ nã pãpã; báyĩ sì ni ìṣe àwọn ènìyàn Nífáì wà ní ipò àìdánilójú àti ewu, l’áìṣírò fún ìṣẹ́gun nlá tí nwọ́n tiní lórí àwọn ará Lámánì, àti ayọ̀ nlá tí nwọ́n ti ní nítorí ìtúsílẹ̀ nwọn nípa ọwọ́ Olúwa. Báyĩ ni a ríi bí àwọn ọmọ ènìyàn ṣe yára tó láti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run nwọn, bẹ̃ni, bí nwọ́n ṣe yára tó láti ṣe àìṣedẽdé, àti láti ṣìnà nípasẹ̀ ẹni búburú nnì. Bẹ̃ni, a sì tún rí ìwà búburú nlá tí ẹyọ ènìyàn kan tí ó burú púpọ̀ lè mú kí ó ṣẹlẹ̀ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn. Bẹ̃ni, a ríi pé Amalikíà, nítorípé ó jẹ́ ẹni ọlọ́gbọ́n àrekérekè àti ẹni tĩ máa sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn púpọ̀, pé ó darí ọkàn àwọn ènìyàn púpọ̀ sí ṣíṣe búburú; bẹ̃ni àti láti lépa láti pa ìjọ Ọlọ́run run, àti láti pa ìpilẹ̀ṣẹ̀ òmìnira èyítí Ọlọ́run ti fifún nwọn, tàbí ìbùkún nnì èyítí Ọlọ́run ti rán wa sí orí ilẹ̀ ayé nítorí àwọn olódodo. Àti nísisìyí ó sì ṣe pé nígbàtí Mórónì, ẹnití í ṣe olórí ológun àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, ti gbọ́ nípa àwọn ìyapa wọ̀nyí, ó bínú sí Amalikíà. Ó sì ṣe tí ó fa ẹ̀wù rẹ̀ ya; tí ó sì mú ìrépé nínú rẹ̀, ó sì kọ lé orí rẹ̀—Ní ìrántí Ọlọ́run wa, ẹ̀sìn wa, àti òmìnira, àti àlãfíà wa, àwọn ìyàwó wa, àti àwọn ọmọ wa—ó sì soó mọ́ ìkangun ọ̀pá kan. Ó sì dé ìhámọ́ra àṣíborí rẹ̀, àti àwo àyà rẹ̀, àti àwọn asà àti apata rẹ̀, ó sì de ìhámọ́ra rẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀; ó sì mú ọ̀pá nã, èyítí ẹ̀wú rẹ̀ tí ó ya wà ní ìkangun rẹ̀, (ó sì pẽ ní àsíá òmìnira) ó sì wólẹ̀ lórí ilẹ̀, ó sì gbàdúrà tagbáratagbára sí Ọlọ́run rẹ̀ kí ìbùkún òmìnira lè bà lé àwọn arákùnrin rẹ̀, níwọ̀n ìgbàtí agbo àwọn Krístíánì bá fi lè kù tí yíò ní ilẹ̀ nã ní ìní— Nítorí báyĩ ni gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú Krístì nítọ́tọ́, tí nwọ́n jẹ́ ti ìjọ Ọlọ́run njẹ́ pípè láti ọwọ́ àwọn tí kò jẹ́ ti ìjọ Ọlọ́run. Àwọn tí nwọ́n sì jẹ́ ti ìjọ nã jẹ́ olódodo; bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí nwọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ òtítọ́ nínú Krístì, gba orúkọ Krístì tayọ̀tayọ̀, tàbí Krístíánì ni a ti npè nwọ́n, nítorí ti ìgbàgbọ́ nwọn nínú Krístì èyítí nbọ̀wá. Nítorínã ẹ̀wẹ̀, ní àkokò yĩ, Mórónì gbàdúrà pé kí ìjàòmìnira àwọn Krístíánì, àti ti ilẹ̀ nã kí ó rí ojúrere Ọlọ́run. Ó sì ṣe pé nígbàtí ó ti fi tọkàn-tọkàn gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó pe gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà gũsù ilẹ̀ nã ní Ibi-Ahoro, bẹ̃ni, àti ní ṣókí, gbogbo ilẹ̀ nã, pẹ̀lú èyítí ó wà ní ìhà àríwá àti ní ìhà gũsù—Ilẹ̀ ãyò, àti ilẹ̀ òmìnira. Ó sì wípé: Dájudájú Ọlọ́run kì yíò jẹ́ kí àwa, tí nwọ́n ti pẹ̀gàn wa nítorípé a gba orúkọ Krístì, kí nwọ́n borí wa kí nwọ́n sì pa wá run, títí àwa yíò fi múu wá sórí wa nípasẹ̀ ìwàirékọjá wa. Nígbàtí Mórónì sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó kọjá lọ sí ãrin àwọn ènìyàn nã, tí ó sì nju ìrépé ẹ̀wú rẹ̀ ní òfúrufú, pé kí gbogbo nwọn lè rí ohun tí òun ti kọ lé ìrépé ẹ̀wù rẹ̀ nã, tí ó sì nkígbe pẹ̀lú ohùn rara, wípé: Ẹ kíyèsĩ, ẹnìkẹ́ni tí yíò bá mú àṣíá yĩ dúró lórí ilẹ̀ yĩ, kí nwọ́n jáde wá ní agbára Olúwa, kí ó sì dá májẹ̀mú pé nwọn yíò mú ẹ̀tọ́ nwọn dúró, àti ẹ̀sìn nwọn, kí Olúwa Ọlọ́run kí ó lè bùkún nwọn. Ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti ṣe ìkéde àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kíyèsĩ, àwọn ènìyàn nã sáré wá pẹ̀lú ìhámọ́ra nwọn ní ẹ̀gbẹ́ nwọn, tí nwọ́n fa ẹ̀wù nwọn ya gẹ́gẹ́bí àmì, tàbí gẹ́gẹ́bí májẹ̀mú, pé nwọn kò ní kọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn sílẹ̀; tàbí, kí a wípé, bí nwọ́n bá ré àwọn òfin Ọlọ́run kọjá, tàbí kí nwọ́n ṣubú sínú ìrékọjá, tí ojú sì tì nwọ́n láti gba orúkọ Krístì, Olúwa yíò fà nwọ́n ya àní gẹ́gẹ́bí nwọn ti ṣe fa ẹ̀wù nwọn ya. Nísisìyí èyí ni májẹ̀mú tí nwọ́n dá, nwọ́n sì bọ́ ẹ̀wù nwọn sí abẹ́ ẹsẹ̀ Mórónì, nwọ́n sì wípé: Àwa bá Ọlọ́run wa dá májẹ̀mú, pé àwa ó parun, àní gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin wa ní ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà àríwá, bí àwa bá ṣubú sínú ìrékọjá; bẹ̃ni, òun yíò fi wá sí abẹ́ ẹsẹ̀ àwọn ọ̀tá wa, àní gẹ́gẹ́bí àwa ti ṣe bọ́ ẹ̀wù wa sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ fún ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀, bí àwa bá ṣubú sínú ìrékọjá. Mórónì wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, iṣẹ́kù irú-ọmọ Jákọ́bù ni àwa í ṣe; bẹ̃ni, ìṣẹ́kù irú-ọmọ Jósẹ́fù ni àwa í ṣe, ẹ̀wù ẹnití àwọn arákùnrin rẹ̀ fàya sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrépé; bẹ̃ni àti nísisìyí kíyèsĩ, ẹ́ jẹ́ kí àwa ó rántí láti pa òfin Ọlọ́run mọ́, láìjẹ́bẹ̃ àwọn arákùnrin wa yíò fa ẹ̀wù wa ya, nwọn ó sì gbé wa sínú tũbú, tàbí kí nwọn tà wá, tàbí pa wá. Bẹ̃ni, ẹ jẹ́ kí a pa òmìnira wa mọ́ gẹ́gẹ́bí ìyókù àwọn àtẹ̀lé Jósẹ́fù; bẹ̃ni, ẹ jẹ́ kí a rántí àwọn ọ̀rọ̀ Jákọ́bù, ṣãjú ikú rẹ̀, nítorí kíyèsĩ, ó ríi pé apá kan nínú ìrépé ẹ̀wù Jósẹ́fù wà ní ìpamọ́ tí kò sì gbó. O sì wípé—Àní gẹ́gẹ́bí ìrépé ẹ̀wù ọmọ mi yĩ ṣe wà ní ìpamọ́, bẹ̃ nã ni ìyókù àwọn àtẹ̀lé irú-ọmọ ọmọ mi yíò wà ní ìpamọ́ nípa ọwọ́ Ọlọ́run, tí yíò sì mú nwọn lọ sí ọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí àwọn irú-ọmọ Jósẹ́fù yókù yíò sì parun, àní gẹ́gẹ́bí ìrépé ẹ̀wù rẹ̀. Nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, ohun yĩ fún ọkàn mi ní ìbànújẹ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ọkàn mi yọ̀ nínú ọmọ mi, nítorí ti apá kan irú-ọmọ rẹ̀ nnì èyítí a ó mú lọ sí ọ́dọ̀ Ọlọ́run. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èyí ni èdè Jákọ́bù. Àti nísisìyí tani ó mọ̀ bóyá ìyókù àwọn àtẹ̀lé irú-ọmọ Jósẹ́fù, èyítí yíò parun gẹ́gẹ́bí ti ẹ̀wù rẹ̀, ni àwọn tí nwọn ti yapa kúrò lára wa? Bẹ̃ni, àti pãpã yíò jẹ́ àwa fúnra wa bí àwa kò bá dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ Krístì. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán ó jáde lọ ó sì tún ránṣẹ́ lọ sí gbogbo apá ilẹ̀ nã níbití ìyapa wà, ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí nwọn ní ìfẹ́ láti di òmìnira nwọn mú papọ̀, láti tako Amalikíà àti àwọn tí nwọ́n ti yapa, tí nwọn npè ní àwọn ará Amalikíà. Ó sì tún ṣe nígbàtí Amalikíà ríi pé àwọn ènìyàn Mórónì pọ̀ púpọ̀ ju àwọn ará Amalikíà lọ—tí ó sì ríi pé àwọn ènìyàn òun nṣiyèméjì nípa àìṣègbè tí nbẹ nínú ìjà èyítí nwọ́n ti dáwọ́lé—nítorínã, nítorípé ó bẹ̀rù pé òun kò ní borí, ó mú nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣetán nwọ́n sì kọjá lọ sínú ilẹ̀ Nífáì. Nísisìyí Mórónì wòye pé àwọn ará Lámánì kò lè lágbára mọ́; nítorínã o gbèrò láti dínàmọ́ àwọn ará Amalikíà, tàbí kí ó mú nwọn kí ó sì kó nwọn padà, kí ó sì pa Amalikíà; bẹ̃ni, nítorítí ó mọ̀ pé yíò rú àwọn ará Lámánì sókè sí ìbínú sí nwọn, tí yíò sì mú nwọn wá láti bá nwọn jagun; èyí ni ó sì mọ̀ pé Amalikíà yíò ṣe láti lè mú ète rẹ̀ ṣẹ. Nítorínã Mórónì rọ́ pé ó tọ́ fún òun láti kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, tí nwọ́n ti kó ara nwọn jọ, tí nwọ́n sì ti gbé ìhámọ́ra ogun wọ̀, tí nwọ́n sì ti dá májẹ̀mú ìwàlálãfíà—ó sì ṣe tí ó kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ tí nwọ́n s ì kọjá lọ pẹ̀lú àwọn àgọ́ nwọn sínú aginjù, láti dínà mọ́ Amalikíà nínú aginjù. Ó sì ṣe tí ó ṣe gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ̀, tí ó sì kọjá lọ sínú aginjù, tí ó sì lọ ṣíwájú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Amalikíà. Ó sì ṣe tí Amalikíà sá pẹ̀lú díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀, tí a sì fi àwọn tí ó kù lé ọwọ́ Mórónì tí ó sì kó nwọn padà lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Nísisìyí, Mórónì nítorítí ó jẹ́ ẹni tí àwọn onídàjọ́ àgbà àti ohùn àwọn ènìyàn nã yàn, nítorínã ó ní àṣẹ bí ó bá ti fẹ́ lórí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, láti fi lọ́lẹ̀ àti láti lọ́ lórí nwọn. Ó sì ṣe tí ẹnìkẹ́ni nínú àwọn ará Amalikíà tí kò bá dá májẹ̀mú láti ti ìjà-òmìnira nnì lẹ́hìn, láti ní ìjọba olómìnira, ni ó mú kí nwọ́n pa; díẹ̀ sì ni àwọn tí ó sẹ́ májẹ̀mú òmìnira nã. Ó sì tún ṣe pẹ̀lú, tí ó mú kí a ta àṣíá òmìnira nã sókè lórí gbogbo ilé ìṣọ́ gíga tí ó wà ní gbogbo ilẹ̀ nã, èyítí àwọn ará Nífáì ní ní ìní; báyĩ sì ni Mórónì fi àsíá òmìnira lélẹ̀ lãrín àwọn ará Nífáì. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ní àlãfíà ní ilẹ̀ nã; bẹ̃ sì ni nwọ́n wà lálãfíà ní ilẹ̀ nã títí di ìgbà tí ọdún kọkàndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ fẹ́rẹ̀ dópin. Hẹ́lámánì àti àwọn olórí àlùfã nã pẹ̀lú ṣe àkóso nínú ìjọ nã; bẹ̃ni, àní fún ìwọ̀n ọdún mẹ́rin ni nwọ́n ní ọ̀pọ̀ àlãfíà, àti ayọ̀ ní ti ìjọ nã. Ó sì ṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kú, nínú ìgbàgbọ́ pé ẹ̀mí nwọn ti di ìràpadà nípasẹ̀ Jésù Krístì Olúwa; bẹ̃ sì ni nwọ́n jáde kúrò láyé pẹ̀lú ìdùnnú. Àwọn míràn wà tí nwọ́n kú pẹ̀lú àìsàn ìgbóná-ara, èyítí ó wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ nã ní àwọn àkokò kan nínú ọdún—ṣùgbọ́n kì í ṣe ìgbóná-ara ni ó pa nwọ́n tó bẹ̃, nítorípé Ọlọ́run ti pèsè àwọn ewéko àti egbò dídára tí yíò mú àwọn àrun nã kúrò, àwọn èyítí íkọlu ènìyàn gẹ́gẹ́bí afẹ́fẹ́ ilẹ̀— Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó kú lẹ́hìn tí nwọ́n ti di arúgbó; àwọn tí nwọ́n sì kú nínú ìgbàgbọ́ nínú Krístì ní ayọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́bí àwa ṣe gbọ́dọ̀ mọ̀. 47 Amalikíà fi ìwà àrékérekè, ìpànìyàn, àti rìkíṣí di ọba àwọn ará Lámánì—Àwọn ará Nífáì tí ó yapa jẹ́ oníwà búburú àti ìkà ènìyàn ju àwọn ará Lámánì lọ. Ní ìwọ̀n ọdún 72 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí a ó padà lórí àkọsílẹ̀ wa lọ sí ti Amalikíà àti àwọn tí nwọ́n ti sá pẹ̀lú rẹ̀ wọ inú aginjù lọ; nítorí, ẹ kíyèsĩ, ó ti mú àwọntí ó lọ pẹ̀lú rẹ̀, tí nwọ́n sì kọjá lọ sínú ilẹ̀ Nífáì lãrín àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì rú ìbínú àwọn ará Lámánì sókè sí àwọn ènìyàn Nífáì, tóbẹ̃ tí ọba àwọn ará Lámánì fi ìkéde ránṣẹ́ jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀, pé kí nwọ́n pé jọ pọ̀ láti tún lọ bá àwọn ará Nífáì jagun. Ó sì ṣe nígbàtí ìkéde nã ti lọ sí ãrin nwọn ẹ̀rù bà nwọ́n gidigidi; bẹ̃ni, nwọn bẹ̀rù láti máṣe ti ọba, nwọ́n sì tún bẹ̀rù láti lọ bá àwọn ará Nífáì jagun kí nwọ́n má bã pàdánù ẹ̀mí nwọn. O sì ṣe tí nwọn kò ṣeé, tàbí pé púpọ̀ nínú nwọn kò ṣe ìgbọràn sí òfin ọba nã. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí ọba bínú nítorí ìwà àìgbọràn nwọn; nítorínã ó fún Amalikíà ní àṣẹ lórí apá kan ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ nnì èyítí ó ṣe ìgbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀, ó sì pã láṣẹ fún un pé kí ó lọ fi ipá mú nwọn gbé ohun ìjà ogun. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èyí ni ìfẹ́ inú Amalikíà; nítorípé ènìyàn alárèkérekè ni í ṣe fún ibi ṣíṣe, nítorínã ni ó ṣe pa ète yĩ ní ọkàn rẹ̀ láti yọ ọba àwọn ará Lámánì kúrò lórí oyè. Àti nísisìyí tí ó sì ti gba àṣẹ lórí àwọn ará Lámánì nnì tí nwọ́n nṣe ti ọba nã; ó sì wá ọ̀nà láti rí ojú rere àwọn tí nwọn kò ṣe ìgbọràn; nítorínã ó jáde lọ sí ibi tí à npè ní Onídà, nítorípé nibẹ ni gbogbo àwọn Lámánì ti salọ; nítorípé nwọ́n ríi tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun nbọ̀wá, àti pé nwọ́n rò wípé nwọ́n ntọ̀ nwọ́n wá láti pa nwọ́n run, nítorínã nwọ́n sá lọ sí Onídà, lọ sí ibití nwọ́n kó àwọn ohun ìjà-ogun pamọ́ sí. Nwọ́n sì ti yan ọkùnrin kan láti jẹ́ ọba àti olórí nwọn, nítorítí nwọ́n ti pinnu nínú ọkàn nwọn pé nwọ́n kò ní gbà kí ọba ó mú nwọn lọ kọlũ àwọn ará Nífáì. Ó sì ṣe ti nwọ́n kó ara nwọn jọ lórí òkè gíga nnì èyítí nwọn npè ní Ántípà, ní ìmúrasílẹ̀ fún ogun. Nísisìyí kì í ṣe èrò inú Amalikíà láti bá nwọn jagun gẹ́gẹ́bí ọba ti pã láṣẹ; ṣùgbọ́n, ẹ kíyèsĩ, èrò inú rẹ̀ ni láti rí ojú rere ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, láti lè di olùdarí nwọn kí òun sì yọ ọba nã kúrò lórí oyè kí ó sì gba ìjọba nã. Ẹ sì kíyèsĩ, ó sì ṣe tí ó mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun tirẹ̀ pàgọ́ nwọn sínú àfonífojì èyítí ó wà lẹba òkè gíga Ántípà. Ó sì ṣe nígbàtí ó di alẹ́ ni ó rán ikọ̀ oníṣẹ́ ní ìkọ̀kọ̀ lọ sí òkè gíga Ántípà, pé kí olórí àwọn tí ó wà lórí òkè gíga nã, ẹnití orúkọ rẹ̀ í ṣe Léhọ́ntì, pé kí ó sọ̀kalẹ̀ wá sí ìsàlẹ̀ òkè gíga nã, nítorítí òun ní ìfẹ́ láti bã sọ̀rọ̀. Ó sì ṣe nígbàtí Léhọ́ntì gbọ́ iṣẹ́ nã òun kò dá àbá láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ òkè gíga nã. O sì ṣe tí Amalikíà tún ránṣẹ́ ní ìgbà kejì, pé òun fẹ́ kí ó sọ̀kalẹ̀ wá. O sì ṣe tí Léhọ́ntì kò ṣe bẹ̃; ó sì tún rán ikọ̀ oníṣẹ́ nã ní ìgbà kẹ́ta. Ó sì ṣe nígbàtí Amalikíà ríi pé òun kò lè mú kí Léhọ́ntì sọ̀kalẹ̀ wá kúrò lórí òkè gíga nã, ni ó kọjá lọ sórí òkè nã, nítòsí ibùdó Léhọ́ntì; ó sì tún ránṣẹ́ ní ìgbà kẹ́rin sí Léhọ́ntì, pé òun fẹ́ kí ó sọ̀kalẹ̀ wá, àti pé kí ó mú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ dání pẹ̀lú rẹ̀. Ó sì ṣe nígbàtí Léhọ́ntì sì ti sọ̀kalẹ̀ wá pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ tọ Amalikíà wá, ni Amalikíà fẹ́ kíó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ní òru, kí nwọ́n sì ká àwọn ènìyàn nnì tí ọba ti fún òun láṣẹ lórí nwọn mọ́ àwọn ibùdó nwọn, àti pé òun yíò fi nwọ́n lé ọwọ́ Léhọ́ntì, bí yíò bá fi òun (Amalikíà) ṣe igbá kejì lórí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nã. Ó sì ṣe tí Léhọ́ntì sọ̀kalẹ̀ wá pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nwọ́n sì yí àwọn ọmọ ogun Amalikíà ká, tí ó jẹ́ wípé kí nwọ́n tó jí ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Léhọ́ntì ti yí nwọn ká. Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n ríi pé nwọ́n ti yí nwọ́n ká, nwọ́n ṣípẹ̀ pẹ̀lú Amalikíà pé kí ó jẹ́ kí nwọ́n darapọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin nwọn, kí nwọ́n má bã parun. Ní báyĩ eleyĩ ni ohun tí Amalikíà fẹ́. Ó sì ṣe tí ó sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yọ, ní ìlòdìsí àṣẹ ọba. Nisisinyi èyí sì ni ohun tí Amalikíà fẹ́, kio lè mú rírọ ọba lóyè di ṣíṣe èyítí í ṣe ète rẹ̀. Nísisìyí ó jẹ́ àṣà lãrín àwọn ará Lámánì, bí a bá pa olórí àgbà nwọn, láti yan ẹnití í ṣe igbá kejì láti jẹ́ olórí àgbà nwọn. Ó sì ṣe tí Amalikíà mú kí ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa fún Léhọ́ntì ní májèlé jẹ ní dẹ́idíẹ̀, tí ó sì kú. Nísisìyí, nígbàtí Léhọ́ntì ti kú, àwọn ará Lámánì yan Amalikíà láti jẹ́ olórí-ológun àgbà nwọn. Ó sì ṣe tí Amalikíà lọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ (nítorítí ó ti rí ìfẹ́-inú rẹ̀ gbà) sí ilẹ̀ Nífáì, sí ìlú-nlá Nífáì, èyítí í ṣe olú-ìlú. Ọba sì jáde wá láti pàdé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ, nítorítí ó rò pé Amalikíà ti jíṣẹ́ tí òun rán an, àti pé Amalikíà ti kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó pọ̀ púpọ̀ jọ láti lọ íkọlu àwọn ará Nífáì nínú ogun. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, bí ọba ṣe jáde wá ípàdé rẹ̀, Amalikíà mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ ípàdé ọba. Nwọ́n sì lọ nwọ́n sì wólẹ̀ níwájú ọba, bí èyítí nwọ́n fẹ́ bọ̀wọ̀ fún un nítorí títóbi rẹ̀. Ó sì ṣe tí ọba na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti gbé nwọn sókè, gẹ́gẹ́bí àṣà àwọn ará Lámánì, fún àmì àlãfíà, àṣà èyítí nwọ́n ti kọ́ lọ́dọ̀ àwọn ará Nífáì. Ó sì ṣe nígbàtí ó ti gbé ẹni àkọ́kọ́ sókè kúrò nílẹ̀, kíyèsĩ ó sì gún ọba nã lọ́bẹ lọ sínú ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀. Nísisìyí àwọn ìránṣẹ́ ọba sá; àwọn ìránṣẹ́ Amalikíà sì kígbe sókè, wípé: Ẹ kíyèsĩ, àwọn ìránṣẹ́ ọba ti gún un lọ́bẹ lọ sínú ọkàn, ó sì ti ṣubú lulẹ̀ nwọ́n sì ti sá lọ; ẹ kíyèsĩ, ẹ wá wọ́. Ó sì ṣe tí Amalikíà pàṣẹ pé kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jáde lọ kí nwọ́n sì wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọba nã; nígbàtí nwọ́n sì ti dé ibẹ̀, tí nwọ́n sì rí ọba nã tí ó dùbúlẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀, Amalikíà ṣe bí èyítí ó bínú, ó sì wípé: Ẹnìkẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn ọba, ẹ jẹ́ kí ó jáde lọ, kí ó sì sá tẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kí ó sì pa nwọ́n. Ó sì ṣe ti gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn ọba nã, nígbàtí nwọn gbọ́ ọ̀rọ̀ yĩ, wọ́n jáde lọ nwọ́n sì sá tẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ ọba nã. Nísisìyí nígbàtí àwọn ìránṣẹ́ ọba rí ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan tí ó nsá tẹ̀lé nwọn, ẹ̀rù tún bà nwọ́n, nwọ́n sì sá wọ inú aginjù lọ, nwọn sì dé inú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà nwọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ará Ámọ́nì. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun èyítí ó sá tẹ̀lé nwọn sì padà, lẹ́hìn tí nwọ́n ti sá tẹ̀lé nwọn lórí asán; báyĩ sì ni Amalikíà, nípa ọ̀nà ẹ̀tàn rẹ̀, ṣe rí ìfẹ́ ọkàn àwọn ènìyàn nã gbà. Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì ó wọ inú ìlú-nlá Nífáì lọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, ó sì mú ìlú nã ní ìní. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí ayaba, nígbàtí ó ti gbọ́ pé nwọ́n ti pa ọba—nítorítí Amalikíà ti rán ikọ̀ oníṣẹ́ sí ayaba nã láti sọ fún un pé àwọn ìránṣẹ́ ọba ti pa ọba nã, pé òun ti sá tẹ̀lé nwọn pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun òun, ṣùgbọ́n asán ni èyí já sí, nwọ́n sì ti sálọ— Nítorínã, nígbàtí ayaba nã gbọ́ iṣẹ́ yĩ ó ránṣẹ́ sí Amalikíà, pé òun fẹ́ kí ó dá àwọn ènìyàn ìlú nã sí; àti pé òun tún fẹ́ kí ó wá bẹ òun wò; àti pé òun tún fẹ́ kí ó mú àwọn ẹlẹ́rĩ dání láti ṣe ìjẹ́rĩ nípa ikú ọba nã. Ó sì ṣe tí Amalikíà mú ìránṣẹ́ kan nã èyítí ó pa ọba, àti gbogbo àwọn tí nwọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, nwọ́n sì tọ ayaba nã lọ, sí ibití ó joko sí; gbogbo nwọn sì jẹ́ ẹ̀rí níwájú rẹ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ ọba ni ó pã; nwọ́n sì tún sọ wípé: Nwọ́n ti sálọ; njẹ́ èyí kò ha jẹ́ ẹ̀rí nípà nwọn? Báyĩ ni nwọ́n sì ṣe tẹ́ ayaba nã lọ́rùn nípa ikú ọba. Ó sì ṣe tí Amalikíà nwá ojú rere ayaba, ó sì fi ṣe aya; báyĩ nìpa ọ̀nà ẹ̀rú rẹ̀, àti nípa ìrànlọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ alarèkérekè rẹ̀, ó gba ìjọba nã; bẹ̃ni, nwọ́n kã kún ọba jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã, lãrín gbogbo àwọn ènìyàn àwọn ará Lámánì, tí nwọn í ṣe àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Lẹ́múẹ́lì àti àwọn ará Íṣmáẹ́lì, àti gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò lára àwọn ará Nífáì, láti ìgbà ìjọba Nífáì títí dé àkokò yĩ. Nísisìyí àwọn olùyapa wọ̀nyí, ní ìkọ́ni àti ìmọ̀ kan nã láti ọwọ́ àwọn ará Nífáì, bẹ̃ni, nwọ́n ní ìkọ́ni nínú ìmọ̀ kannã nípa Olúwa, bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu pé, láìpẹ́ lẹhin ìyapa wọn nwọ́n sì di líle sii ti nwọ́n sì sé àyà nwọn le, nwọ́n ya ẹ̀hànnà síi, nwọ́n burú síi, nwọ́n sì rorò ju àwọn ará Lámánì lọ—tí nwọn ngbé àṣà àwọn ará Lamánì wọ̀; tí nwọ́n sì nhùwà ọ̀lẹ, àti onírũrú ìwà ìfẹ́kúfẹ; bẹ̃ni, tí nwọ́n sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run nwọn pátápátá. 48 Amalikíà rú ọkàn àwọn ará Lámánì sókè sí àwọn ará Nífáì—Mórónì ṣe ìmúrasílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti jà ìjà-òmìnira ti àwọn Krìstìánì—Ó yọ̀ nínú ìtúsílẹ̀ àti òmìnira ó sì jẹ́ ẹni nlá nínú Ọlọ́run. Ní ìwọ̀n ọdún 72 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe, ní kété tí Amalikíà ti gba ìjọba nã ni ó bẹ̀rẹ̀sí rú ọkàn àwọn ará Lámánì sókè sí àwọn ará Nífáì; bẹ̃ni, ó sì yan àwọn ènìyàn láti bá àwọn ará Lámánì sọ̀rọ̀ láti àwọn ilé ìṣọ́ gíga nwọn, ní ìtako àwọn ará Nífáì. Báyĩ ni ó sì ṣe rú ọkàn nwọn sókè sí àwọn ará Nífáì, tó bẹ̃ tí ó jẹ́ pé ní àkokò tí ọdún kọkàndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ fẹ́rẹ̀ dópin, tí ó sì ti mú ète rẹ̀ di ṣíṣe títí dé àkokò yĩ, bẹ̃ni, tí nwọ́n sì ti fi ṣe ọba lórí àwọn ará Lámánì, ó wá ọ̀nà pẹ̀lúláti jọba lórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ nã, àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì pẹ̀lú. Nítorínã ó ti mú ète rẹ̀ di ṣíṣe, nítorítí ó ti sé àyà àwọn ará Lámánì le tí ó sì ti fọ́ ojú inú nwọn, tí ó sì ti rú ọkàn nwọn sókè ní ìbínú, tó bẹ̃ tí ó sì ti kó ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun jọ láti lọ bá àwọn ará Nífáì jagun. Nítorítí ó ti pinnu láti borí àwọn ará Nífáì kí ó sì mú nwọn ní ìgbèkùn nítorí pípọ̀ tí àwọn ènìyàn rẹ̀ pọ̀. Báyĩ sì ni ó yan àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun lãrín àwọn ará Sórámù, nítorítí nwọ́n ní ìmọ̀ nípa agbára àwọn ará Nífáì, àti ibi ìsádi nwọn, àti àwọn ibi àìlágbára inú ìlú-nlá nwọn; nítorínã ni ó ṣe yàn nwọ́n láti jẹ́ àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun lórí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. Ó sì ṣe tí nwọ́n kó àgọ́ nwọn, tí nwọ́n sì tẹ̀síwájú sí ìhà ilẹ̀ Sarahẹ́múlà nínú aginjù. Nísisìyí ni ó sì ṣe pé bí Amalikíà ṣe ngba agbára nípa ọ̀nà ẹ̀rú, ni Mórónì, ní ìdà kejì, ti nṣe ìmúrasílẹ̀ ọkàn àwọn ènìyàn nã láti jẹ́ olódodo sí Olúwa Ọlọ́run nwọn. Bẹ̃ni, ó ti nfi okun fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, tí ó sì nmú kí nwọ́n kọ́ àwọn odi kékèké, tàbí àwọn ibi ìsádi; pẹ̀lú ìṣù amọ̀ yípo láti ká àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ mọ́, àti mímọ́ odi òkúta yípo gbogbo ìlú-nlá nwọn àti àwọn etí ilẹ̀ nwọn gbogbo; bẹ̃ni, yípo ilẹ̀ nã. Àti ní gbogbo àwọn ibi ìsádi nwọn tí ó ṣe aláìlágbára jùlọ ni ó fi àwọn ọmọ ogun tí ó pọ̀ jùlọ sí; báyĩ sì ni ó dãbò bò tí ó sì fún ilẹ̀ nã ní ágbára èyítí àwọn ará Nífáì ní ní ìní. Báyĩ ni ó sì nṣe ìmúrasílẹ̀ láti se àtìlẹhìn fun òmìnirá nwọn, àwọn ilẹ̀ nwọn, àwọn ìyàwó nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn, àti àlãfíà nwọn, àti pé kí nwọ́n ó lè wà lãyè fún Olúwa Ọlọ́run nwọn, àti pé kí nwọ́n lè gbé èyí nnì tí àwọn ọ̀tá nwọn npè ní ìjà-òmìnira àwọn Krìstìánì ró. Mórónì sì jẹ́ ènìyàn tí ó ní ipá àti agbára; ó jẹ́ ẹnití ó ní òye pípé; bẹ̃ni, ẹnití kò ní inúdídùn sí ìtàjẹ̀sílẹ̀; ẹnití ọkàn rẹ̀ ní áyọ̀ nínú ìtúsílẹ̀ àti òmìnira orílẹ̀-èdè rẹ̀, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò nínú ìdè àti oko ẹrú; Bẹ̃ni, ẹnití ọkàn rẹ̀ kún fún ọpẹ́ sí Ọlọ́run rẹ̀, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfàní àti ìbùkún tí ó ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ̀; ẹnití o ṣiṣẹ́ púpọ̀púpọ̀ fún àlãfíà àti àìléwu àwọn ènìyàn rẹ̀. Bẹ̃ni, ó sì jẹ́ ẹnití ó dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ nínú Krístì, ó sì ti búrà nínú ìbúra láti dãbò bò àwọn ènìyàn rẹ̀, ẹ̀tọ́ rẹ̀ àti orílẹ̀-èdè rẹ̀, àti ẹ̀sìn rẹ̀, àní títí dé títa ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀. Nísisìyí a ti kọ́ àwọn ará Nífáì láti dãbò bò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, àní títí dé ìtàjẹ̀sílẹ̀ bí ó bá di ṣíṣe; bẹ̃ni, a sì tún kọ́ nwọn láti má kọ lu ẹnìkẹ́ni láéláé, bẹ̃ni, láti má gbé idà sókè sí ẹnìkẹ́ni láéláé àfi sí ẹnití í ṣe ọ̀tá, àfi fún pípa ẹ̀mí nwọn mọ́. Eyĩ sì ni ìgbàgbọ́ nwọn, pé nípa ṣíṣe eleyĩ Ọlọ́run yíò mú nwọn ṣe rere lórí ilẹ̀ nã, tàbí kí a wípé, bí nwọ́n bá jẹ́ olódodo ní pípa òfin Ọlọ́run mọ́ pé òun yíò mú nwọn ṣe rere lórí ilẹ̀ nã;bẹ̃ni, kìlọ̀ fún nwọn láti sá, tàbí láti múrasílẹ̀ fún ogun, ní ti ewu tí ó bá wà fún nwọn; Àti pẹ̀lú, pé Ọlọ́run yíò sọọ́ di mímọ̀ fún nwọn ibi tí nwọn yíò lọ láti dábọ́bò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, àti nípa ṣíṣe eleyĩ, Olúwa yíò kó nwọn yọ; èyí sì ni ìgbàgbọ́ Mórónì, ọkàn rẹ̀ sì yọ̀ púpọ̀ nínú rẹ, kĩ ṣe nínú ìtàjẹ̀sílẹ̀ ṣùgbọ́n nínú ṣíṣe rere, nínú pipa àwọn ènìyàn rẹ mọ, nínú pípa òfin Ọlọ́run mọ́, bẹ̃ni, àti yíyẹra fún àìṣedẽdé. Bẹ̃ni, lọ́tọ́, lọ́tọ́ ni mo wí fún nyín, bí gbogbo ènìyàn bá wà, àti ti nwọn sì wà, àti ti nwọn yíò si wa bí Mórónì, kíyèsĩ, gbogbo àwọn agbára ọ̀run àpãdì yíò di aláìlágbára títí láéláé; bẹ̃ni, èṣù kì bá ti lágbára lórí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn. Kíyèsĩ, ó jẹ́ ẹnití ó dàbí Ámọ́nì, ọmọ Mòsíà, bẹ̃ni, àti àwọn ọmọ Mòsíà yókù pẹ̀lú, bẹ̃ni, àti Álmà àti àwọn ọmọ rẹ̀, nítorítí gbogbo nwọn jẹ́ ẹni Ọlọ́run. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kò ṣe aláì ṣiṣẹ́ lãrín àwọn ènìyàn nã bí ti Mórónì; nítorítí nwọ́n wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nwọ́n sì ṣe ìrìbọmi fún gbogbo ẹni tí yíò bá tẹ́tísí ọ̀rọ̀ nwọn sí ti ìrònúpìwàdà. Báyĩ ni nwọ́n sì ṣe jáde lọ, àwọn ènìyàn nã sì rẹ ara nwọn sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ nwọn, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi rí ojú rere Olúwa lọ́pọ̀lọpọ̀, báyĩ sì ni nwọ́n ṣe bọ́ lọ́wọ́ ogun àti ìjà lãrín ara nwọn, bẹ̃ni, àní fún ìwọ̀n ọdún mẹ́rin. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí mo ti wí ní ìṣãjú, ní àkokò t í ọdún kọkàndínlógún fẹ́rẹ̀ dópin, bẹ̃ni, l’áìṣírò àlãfíà wà lãrín ara nwọn, a mú nwọn bá àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì jà pẹ̀lú ìlọ́ra. Bẹ̃ni, ní kukuru, àwọn ogun nwọn pẹ̀lú àwọn ará Lámánì kò tán fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, l’áìṣírò nwọ́n ní ìlọ́ra púpọ̀ láti bá nwọn jà. Nísisìyí, nwọ́n kẹ́dùn láti gbé ohun ìjà-ogun ti àwọn ará Lámánì, nítorítí nwọn kò ní inú dídùn sí ìtàjẹ̀sílẹ̀; bẹ̃ni, èyí nìkan sì kọ́—nwọn kẹ́dùn láti jẹ́ ipa tí a ó fi rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin nwọn jáde kúrò nínú ayé yĩ lọ sínú ayérayé, ní aimurasílẹ̀ láti bá Ọlọ́run nwọn pàdé. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọn kò lè gbà láti fi ẹ̀mí nwọn lélẹ̀, kí àwọn tí ó fi ìgbà kan rí jẹ́ arákùnrin nwọn ó pa àwọn aya àti ọmọ nwọn nípasẹ̀ ìwà ìkà òun ìpãnle nwọn, bẹ̃ni, tí nwọ́n sì ti yapa kúrò nínú ìjọ nwọn, tí nwọ́n sì ti kúrò lọ́dọ̀ nwọn, tí nwọ́n sì ti lọ láti pa nwọ́n run nípa dídarapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì. Bẹ̃ni, nwọn kò lè gbà kí àwọn arákùnrin nwọn yọ̀ lé ẹ̀jẹ̀ àwọn ará Nífáì, níwọ̀n ìgbàtí àwọn kan bá wà tí ó npa òfin Ọlọ́run mọ́, nítorípé ìlérí Olúwa ni pé, bí nwọ́n bá pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ nwọn yíò ṣe rere ní ilẹ̀ nã. 49 Àwọn ará Lámánì ti ngbógun kó lè mú àwọn ìlú-nlá Amonáíhà àti Nóà tí a mọdisí—Amalikíà fi Ọlọ́run bú, ó sì pinnu láti mu ẹ̀jẹ̀ Mórónì—Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀tẹ̀síwájú láti mú ìjọ nã lọ́kàn le. Ní ìwọ̀n ọdún 72 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe ní oṣù kọkànlá ọdún kọkàndínlógún, ní ọjọ́ kẹwa oṣù nã, nwọ́n rí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì tí nwọ́n nbọ̀wá sínú ilẹ̀ Amonáíhà. Àti kíyèsĩ, nwọ́n ti tún ìlú-nlá nã kọ́, Mórónì sì ti fi ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan sí àyíká ìlú-nlá nã, nwọ́n sì ti mọ́ ẹrùpẹ̀ jọ yíká láti dãbò bò nwọ́n lọ́wọ́ ọfà àti òkúta kékèké àwọn ará Lámánì; nítorí kíyèsĩ, òkúta kékèké àti ọfà ni nwọ́n fi jà. Ẹ kíyèsĩ, mo sọ wípé nwọ́n ti tún ìlú-nlá Amonáíhà kọ́. Mo wí fún yín, bẹ̃ni, pé nwọn tún apá kan kọ́; àti nítorípé àwọn ará Lámánì ti pa á run ní ìgbà kan rí nítorí àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã, nwọ́n rò wípé yíò tún rọrùn fún nwọn láti mú ní ìgbà yĩ. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, báwo ni ìrètí nwọn ti di ṣíṣákì tó; nítorí kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì ti mọ́ odi amọ̀ yí ara nwọn ká, èyítí ó ga tóbẹ̃ tí àwọn ará Lámánì kò lè ju àwọn òkúta àti ọfà nwọn bà nwọ́n, bẹ̃ sì ni nwọn kò lè tọ̀ nwọ́n lọ àfi láti ẹnu ọ̀nà nwọn. Nísisìyí ni àkokò yí ẹnu ya àwọn olórí-ológun àgbà àwọn ará Lámánì gidigidi, nítorí ọgbọ́n àwọn ará Nífáì ni ti ìpamọ́ àwọn ibi àbò nwọn. Nísisìyí àwọn olórí àwọn ará Lámánì ti rò wípé, nítorí tí púpọ̀ ní iye nwọn, bẹ̃ni, nwọ́n rò wípé nwọn yíò ní ànfàní láti kọ lù nwọ́n bí nwọn ti í ṣe tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀; bẹ̃ni, nwọ́n si tún ti múrasílẹ̀ pẹ̀lú apata; àti pẹ̀lú ìgbayàogun; nwọ́n sì tún ti múrasílẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀wù awọ-ẹran, bẹ̃ni, ẹ̀wù tí ó ki lọ́pọ̀lọpọ̀ láti bò ìhọ́hò nwọn. Nítorítí nwọ́n sì ti múrasílẹ̀ báyĩ nwọ́n rò wípé nwọn yíò borí àwọn arákùnrin nwọn pẹ̀lú ìrọ̀rùn tí nwọn yíò sì mú nwọn dè nínú àjàgà oko-ẹrú, tàbí kí nwọ́n gba ẹ̀mí nwọn, kí nwọ́n sì pa nwọ́n ní ìpakúpa ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnú nwọn. Ṣùgbọ́n kíyèsí, sí ìyàlẹ́nu nwọn nlá, nwọ́n ti múrasílẹ̀ dè nwọ́n, ní ọ̀nà tí a kò rí rí lãrín àwọn ọmọ Léhì. Nísisìyí, nwọ́n ti múrasílẹ̀ de àwọn ará Lámánì, láti jagun ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Mórónì. O sì ṣe tí àwọn ará Lámánì, tábí àwọn ará Amalikíà, ní ìyàlẹ́nu nlá lórí ìmúrasílẹ̀ fún ogun tí nwọ́n ṣe. Nísisìyí, bí ọba Amalikíà bá ti jáde wá láti inú ilẹ̀ Nífáì, níwájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, bóyá yíò ti mú kí àwọn ará Lámánì kọlũ àwọn ará Nífáì nínú ìlú-nlá tí í ṣe Amonáíhà; nítorí ẹ kíyèsĩ, kò kọ̀ bí nwọ́n bá pa àwọn ènìyàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Amalikíà kò jáde wá sí ójú ogun tìkararẹ̀. Sì kíyèsĩ, àwọn olórí ogun rẹ̀ àgbà kò kọlũ àwọn ará Nífáì nínú ìlú-nlá tí íṣe Amonáíhà, nítorítí Mórónì ti ṣe àtúntò ìṣàkóso lãrín àwọn ará Nífáì, tóbẹ̃ tí ìrètí àwọn ará Lámánì fi ṣákì nípa ti ibi ìsádi nwọn, tí nwọn kò sì lè kọlũ nwọ́n. Nítorínã nwọ́n pẹ̀hìndà sínú aginjù, nwọ́n sì kó àgọ́ nwọn, nwọ́n sì lọ sí apá ilẹ̀ Nóà, nítorítí nwọ́n rò pé ibẹ̀ ni ó tún dárajù lọ láti kọlũ àwọn ará Nífáì. Nítorítí nwọn kò mọ̀ pé Mórónì ti mọ́ odi yíká, tàbí pé ó ti mọ́ odi yíká fún ì dãbò bò ìlú, fún gbogbo ìlú-nlá tí ó wà ní ilẹ̀ nã àti agbègbè nwọn; nítorínã, nwọ́n kọjá lọ sínú ilẹ̀ Nóà pẹ̀lú ìpinnu tí ó dúró ṣinṣin; bẹ̃ni, àwọn olórí-ogun nwọn àgbà jáde wá nwọ́n sì ṣe ìbúra pé àwọn yíò pa àwọn ará ìlú-nlá nã run. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, sí ìyàlẹnu nwọn nlá, ìlú-nlá Nóà, èyítí ó jẹ́ ibi aláìlágbára tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó sì jẹ́ wípé nísisìyí, nípa àwọn Mórónì, ó ti di alágbára, bẹ̃ni, àní tayọ agbára ìlú-nlá Amonáíhà. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, eleyĩ jẹ́ ohun ọgbọ́n fún Mórónì ní ṣíṣe; nítorípé ó ti ròo wípé nwọn yíò bẹ̀rù ní ìlú-nlá Amonáíhà; àti nítorípé bí ìlú-nlá Nóà ṣe jẹ́ ibi aláìlágbára jùlọ nínú ilẹ̀ nã tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorínã nwọn yíò kọjá lọ síbẹ̀ láti bá nwọn jagun; bẹ̃ sì ni ó rí ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn rẹ. Sì kíyèsĩ, Mórónì ti yan Léhì láti jẹ́ olórí ogun àgbà lé àwọn ọmọ ogun ìlú nlá nã lórí; Léhì yĩ kannã ni ẹnití ó bá àwọn ará Lámánì jà nínú àfonífojì tí ó wà ní apá ilà ọ́rùn odò Sídónì. Àti nísisìyí sì kíyèsĩ ó sì ṣe, nígbàtí àwọn ará Lámánì ti ríi pé Léhì ni í ṣe olórí-ogun ìlú-nlá nã, ìrètí nwọn tún ṣákì, nítorítí nwọn bẹ̀rù Léhì púpọ̀púpọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃ àwọn olórí-ogun nwọn àgbà ti búra pẹ̀lú ìbúra láti kọlũ ìlú-nlá nã; nítorínã, nwọn kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn jáde wá. Nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì kò lè wọ inú ibi ìsádi ãbò nwọn nípa ọ̀nà míràn bíkòṣe nípa ẹnu-ọ̀nà nítorí ti gíga odi tí nwọ́n ti mọ, àti jíjìn kòtò tí nwọ́n ti wà yíká, àfi bí nwọ́n bá gba ẹnu ọ̀nà. Báyĩ sì ni àwọn ará Nífáì ti ṣe ìmúrasílẹ̀ láti pa gbogbo àwọn tí yíò lépa láti gùnkè láti wọ inú ibi ìsádi nã nípa ọ̀nà míràn, nípa sísọ àwọn òkúta àti ọfà lù nwọ́n. Báyĩ ni nwọ́n ṣe ìmúrasílẹ̀, bẹ̃ni, ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun nwọn tí ó lágbára jùlọ, pẹ̀lú idà nwọn àti kànnà-kànnà nwọn, láti ké gbogbo àwọn tí yíò lépa láti wá sí ibi ãbò nwọn lulẹ̀ nípa ibi ọ̀nà àbáwọlé; báyĩ sì ni nwọ́n ṣe ìmúrasílẹ̀ láti dábò bò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì. O sì ṣe tí àwọn olórí-ogun àwọn ará Lámánì kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn wá sí ibi ọ̀nà àbáwọlé nã, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bá àwọn ará Nífáì jà, láti lè wọ inú ibi ãbò nwọn; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nwọ́n lé nwọn padà ní onírurú ìgbà, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi pa nwọ́n ní ìpakúpa. Nísisìyí nígbàtí nwọ́n ti ríi pé nwọn kò lè borí àwọn ará Nífáì nípa ọ̀nà àbáwọlé nã, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí fọ́ odi nwọn tí nwọ́n mọ́ kí nwọ́n lè la ọ̀nà fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn, kí nwọ́n lè ní ànfàní ọgbọgba láti jà; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nínú ipa yĩ nwọ́n di píparun lọ́wọ́ àwọn òkúta àti ọfà tí nwọ́n sọ lù nwọ́n; àti pé kàkà kí nwọ́n kún àwọn kòtò nwọn pẹ̀lú erùpẹ̀ tí nwọ́n fi mọ́ odi, àwọn òkú ènìyàn àti àwọn tí ó ti fara gbọgbẹ́ ni ó kún nwọn. Báyĩ ni àwọn ará Nífáì ṣe borí àwọn ọ̀tá nwọn; báyĩ sì niàwọn ará Lámánì ṣe lépa láti pa àwọn ará Nífáì run títí nwọ́n fi pa àwọn olórí-ogun àgbà nwọn gbogbo; bẹ̃ni, nwọ́n sì pa àwọn ará Lámánì tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún; tí ó sì jẹ́ wípé ní ìdà kejì, kò sí ẹyọ kan nínú àwọn ará Nífáì tí a pa. Àwọn bí ãdọ́ta ni ó fara gbọgbẹ́, àwọn tí ọfà àwọn ará Lámánì bá ní ibi ọ̀nà àbáwọlé, ṣùgbọ́n nwọ́n rí ìdábòbò lọ́wọ́ asà nwọn, àti ìgbàyà-ogun nwọn, àti ìhámọ́ra ìbòri-ogun nwọn, tóbẹ̃ tí ó fi jẹ́ wípé ẹsẹ̀ ni nwọ́n ti gbọgbẹ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyítí ó sì pọ̀ púpọ̀. O sì ṣe, pé nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé nwọ́n ti pa olórí-ogun àgbà nwọn, nwọ́n sá wọ inú aginjù lọ. O sì ṣe tí nwọ́n padà sínú ilẹ̀ Nífáì, láti wí fún ọba nwọn, Amalikíà, ẹnití í ṣe ará Nífáì nípa bíbí rẹ̀, nípa àdánù nlá nwọn. O sì ṣe tí ó bínú gidigidi sí àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorípé kò rí ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣe lórí àwọn ará Nífáì; kò rí nwọn mú dè nínú àjàgà oko-ẹrú. Bẹ̃ni, ó bínú gidigidi, ó sì bú Ọlọ́run, àti Mórónì pẹ̀lú, tí ó sì búra nínú ìbúra pé òun yíò mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀; èyí sì rí bẹ̃ nítorípé Mórónì pa òfin Ọlọ́run mọ́ ní ti mímúrasílẹ̀ fún ãbò àwọn ènìyàn rẹ̀. O sì ṣe, ní ìdà kejì, àwọn ará Nífáì fi ọpẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run nwọn, nítorí agbára rẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ tí ó fi gbà nwọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn. Báyĩ sì ni ọdún kọkàndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin. Bẹ̃ni, àlãfíà sì wà lãrín nwọn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtẹ̀síwájú nlá nínú ìjọ-onígbàgbọ́ nã nítorípé nwọ́n fi tọkàn-tọkàn ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyítí Hẹ́lámánì sọ fún nwọn, àti Ṣíblọ́nì, àti Kòríátọ́nì, àti Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn tí a ti yàn nípa ti ẹgbẹ́ mímọ́ Ọlọ́run, tí a sì rì wọn bọmi sí ìrònúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀, tí a sì ti rán nwọn jáde lọ wãsù lãrín àwọn ènìyàn nã. 50 Mórónì mọdisí àwọn ilẹ̀ àwọn ará Nífáì—Nwọ́n kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú-nlá titun—Àwọn ogun àti ìparun kọlũ àwọn ará Nífáì ní àwọn ọjọ́ ìwà búburú àti ìwà ìríra nwọn—Mọ́ríátọ́nì àti àwọn olùyapa rẹ̀ ni Tíákúmì borí—Nífáìhà kú, ọmọ rẹ̀ Pahoránì sì bọ́ sí ipò ìtẹ́ ìdájọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 72 sí 67 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Mórónì kò dáwọ́dúró láti ṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun, tàbí láti ṣe ìdábòbò àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì; nítorítí ó mú kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ kí nwọ́n bẹ̀rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ogún ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, pé kí nwọn ó bẹ̀rẹ̀sí wíwa ilẹ̀ yíká àwọn ìlú-nlá gbogbo, jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ tí àwọn ará Nífáì ní ní ìní. Lórí àwọn òkìtì ilẹ̀ wọ̀nyí ni ó sì ní kí nwọ́n kó àwọn igi lé, bẹ̃ni, àwọn igi nã ni nwọ́n kójọ tó ìwọ̀n gíga ènìyàn, yíká àwọn ìlú-nlá nã. O sì mú kí nwọ́n to àwọn òpó ẹlẹ́nu ṣọ́nṣó lé orí àwọn igi tí nwọ́n tò yíká; nwọn sì ní ágbára nwọ́n sì ga sókè. O sì mú kí nwọ́n kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ gíga tí ó dojúkọ àwọn òpó ẹlẹ́nu ṣónṣó nã, ó sì mú kí nwọ́n kọ́ àwọn ibi ãbò lé orí àwọn ilé ìṣọ́ gíga nã, kí àwọn òkúta àti ọfà àwọn ará Lámánì má lè pa nwọ́n lára. Nwọ́n sì ṣe ìmúrasílẹ̀ fún nwọn pé nwọn yíò lè ju òkúta láti orí nwọn, gẹ́gẹ́bí ó bá ti wù nwọ́n àti gẹ́gẹ́bí agbára nwọn, kí nwọn sì pa ẹnití ó bá lèpa láti kọjá sí itòsí àwọn ògiri ìlú-nlá nã. Báyĩ sì ni Mórónì ṣe ìpèsè ibi ãbò ní ìdojúkọ bíbọ̀ àwọn ọ̀tá nwọn, yíká gbogbo ìlú-nlá nínú gbogbo ilẹ̀ nã. O sì ṣe tí Mórónì mú kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ lọ sínú aginjù tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn; bẹ̃ni, nwọ́n sì lọ nwọ́n sì lé gbogbo àwọn ará Lámánì tí ó wà ní aginjù ìhà ìlà-oòrùn sínú ilẹ̀ nwọn, èyítí ó wà ní ìhà gúsù ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Ilẹ̀ Nífáì sì nà láti apá òkun apá ilà-oòrùn títí dé apá ìwọ̀-oòrùn. O sì ṣe pé nígbàtí Mórónì ti lé gbogbo àwọn ará Lámánì jáde kúrò nínú aginjù ti apá ìlà-oòrùn, tí ó wà ní apá àríwá àwọn ilẹ̀ tĩ ṣe ìní nwọn, ó mú kí àwọn t í ó ngbé inú i l ẹ̀ Sarahẹ́múlà àti nínú ilẹ̀ àyíká lọ sínú aginjù apá ìlà-oòrùn, àní lọ sí ibi ìkángun etí òkun, kí nwọ́n sì ní ilẹ̀ nã ní ìní O sì fi àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun sí apá gúsù, ní ibi ìkángun àwọn ìní nwọn, ó sì mú nwọn láti kọ́ àwọn ibi ãbò láti lè fi ãbò bò àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn àti àwọn ènìyàn nwọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn. Báyĩ ni ó sì mú gbogbo àwọn ibi ãbò àwọn ará Lámánì kúrò ní aginjù ti apá ìlà-oòrùn, bẹ̃ni, àti ní apá ìwọ̀-oòrùn, tí ó dábọ́bò bò ilẹ̀ tí ó wà lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì, lãrín ilẹ̀ Sarahẹ́múlà àti ilẹ̀ Nífáì, láti òkun apá ìwọ̀-oòrùn, èyítí ó ṣàn láti orí odò Sídónì—tí àwọn ará Nífáì sì ní ní ìní gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá, bẹ̃ni, àní gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ nwọ́n. Báyĩ ni Mórónì, pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, tí ó npọ̀ síi lójojúmọ́ nítorí ìdánilójú ìdábòbò tí iṣẹ́ rẹ̀ ti mú jáde fún nwọn, ṣe wá ọ̀nà láti ké ipa àti agbára àwọn ará Lámánì kúrò lórí àwọn ilẹ̀ ìní nwọn, pé kí nwọ́n má lè ní agbára rárá lórí àwọn ilẹ̀ ìní nwọn. O sì ṣe tí àwọn ará Nífáì bẹ̀rẹ̀sí kíkọ́ ìpìlẹ̀ ìlú-nlá kan, nwọ́n sì pe orúkọ ìlú nlá nã ní Mórónì; ó sì wà ní ẹ̀gbẹ́ òkun apá ìlà oòrùn; ó sì wà ní apá gúsù ní etí ibi ìní àwọn ará Lámánì. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí kíkọ́ ìpìlẹ̀ fún ìlú kan ní ãrin ìlú-nlá Mórónì àti ìlú-nlá Áárọ́nì, tí ó sì so etí ilẹ̀ Áárọ́nì àti ti Mórónì pọ̀; nwọ́n sì pe orúkọ ìlú-nlá nã, tàbí ilẹ̀ nã, ní Nífáìhà. Nwọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀sí kíkọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú-nlá ní apá àríwá nínú ọdún kannã, èyítí nwọn npè ní Léhì tí nwọ́n sì kọ́ ní ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀, tí ó wà ní apá àríwá, ní etí bèbè òkun. Báyĩ sì ni ogún ọdún parí. Nínú ipò ìlọsíwájú yĩ ni àwọn ará Nífáì sì wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kọ́kànlélógún nínú ìjọbaàwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì. Nwọ́n sì ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀, nwọ́n sì ní ọrọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀; bẹ̃ni, nwọ́n sì tún bí síi nwọ́n sì lágbára ní ilẹ̀ nã. Báyĩ sì ni a ríi bí gbogbo ìṣesí Olúwa ṣe kún fún ãnú tó tí ó sì tọ́, sí mímú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ sí àwọn ọmọ ènìyàn; bẹ̃ni, a lè ríi pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìjẹ́rìsí, àní ní àkokò yĩ, èyítí ó sọ fún Léhì, wipe: Ìbùkún ni fún ọ àti àwọn ọmọ rẹ; nwọn ó sì jẹ́ alábùkúnfún, níwọ̀n ìgbàtí nwọn yíò bá pa òfin mi mọ́ nwọn yíò ṣe rere lórí ilẹ̀ nã. Ṣùgbọ́n rántí, níwọ̀n ìgbàtí nwọn kò bá pa òfin mi mọ́ a ó ké nwọn kúrò níwájú Olúwa. Àwa sì ríi pé àwọn ìlérí wọ̀nyí ti ní ìjẹ́rìsí fún àwọn ará Nífáì; nítorípé àwọn asọ̀ àti àwọn ìjà nwọn, bẹ̃ni, àwọn ìpànìyàn nwọn, àti àwọn ìkógun nwọn, àwọn ìbọ̀rìṣà nwọn, àwọn ìwà àgbèrè nwọn, àti àwọn ìwà ìríra nwọn, èyítí ó wà lãrín ara nwọn, àwọn ni ó mú ogun àti ìparun bá nwọn. Àwọn tí nwọ́n sì jẹ́ olódodo ní ti pípa òfin Olúwa mọ́ ni a kó yọ ní ìgbà gbogbo, tí ó sì jẹ́ wípé ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àwọn arákùnrin nwọn búburú ni a ti rán sí oko-ẹrú, tàbí sí ti ìparun lọ́wọ́ idà, tàbí sí àjórẹ̀hìn nínú ìgbagbọ́, tí nwọn sì darapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ kò sí irú àkokò tí ayọ̀ tó báyĩ rí lãrín àwọn ènìyàn Nífáì, láti àkokò Nífáì ju àkokò ti Mórónì, bẹ̃ni, àní ní àkokò y ĩ , ní ọdún kọkànlélógún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́. O sì ṣe tí ọdún kejìlélógún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ nã parí pẹ̀lú àlãfíà; bẹ̃ni, àti ọdún kẹtàlélógún pẹ̀lú. O sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹrìnlélógún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí àlãfíà ìbá wà lãrín àwọn ènìyàn Nífáì bíkòbáṣe ti ìjà kan tí ó wà lãrín nwọn lórí ilẹ̀ Léhì, àti ilẹ̀ Mọ́ríátọ́nì, èyítí ó so pọ̀ mọ́ etí ilẹ̀ Léhì; àwọn méjẽjì sì wà ní etí ilẹ̀ tí ó wà ní ibi bèbè òkun. Nítorí kíyèsĩ, àwọn ènìyàn tí ó ní ilẹ̀ Mọ́ríátọ́nì mú apá kan nínú ilẹ̀ Léhì ní ìní; nítorínã ni ìjà líle bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín nwọn, tóbẹ̃ tí àwọn ará Mọ́ríátọ́nì gbé ohun ìjà-ogun kọlũ àwọn arákùnrin nwọn, nwọ́n sì pinnu láti pa nwọ́n pẹ̀lú idà. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ènìyàn tí ó ni ilẹ̀ Léhì ní ìní sálọ sínú àgọ́ Mórónì, nwọ́n sì ṣìpẹ̀ fún un fún ìrànlọ́wọ́; nítorítí kíyèsĩ nwọ́n ko jẹ̀bi. O sì ṣe pé nígbàtí àwọn ènìyàn Mọ́ríátọ́nì, àwọn ti ẹnití orúkọ rẹ̀ íṣe Mọ́ríántọ́nì ndarí, rí i pé àwọn ènìyàn Léhì ti sálọ sí ibi àgọ́ Mórónì, ẹ̀rù bà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì ma wa láti kọlũ nwọ́n kí nwọ́n sì pa nwọ́n run. Nítorínã, Móríántọ́nì tẹ̃ mọ́ nwọn lọ́kàn pé kí nwọ́n sá lọ sínú ilẹ̀ èyítí ó wà ní apá àríwá, èyítí omi nlá bò orí rẹ̀, kí nwọ́n sì ní ilẹ̀ nã èyítí ó wà ní apá àríwá ní ìní. Sì kíyèsĩ, nwọn ìbá ti mú ète yĩ ṣe, (èyítí ìbá jẹ́ ohun àbámọ̀) ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Mọ́ríátọ́nìnítorípé ó jẹ́ onínúfùfù ènìyàn, nítorínã ó bínú sí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, ó sì kọ lù ú ó sì lù ú lọ́pọ̀lọpọ̀. O sì ṣe tí ó sá, ó sì dé inú àgọ́ Mórónì, ó sì sọ ohun gbogbo nípa ọ̀rọ̀ nã fún Mórónì, àti nípa ète nwọn láti sálọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá. Nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, tàbí kí a sọ wípé Mórónì, ní ìbẹ̀rù pé nwọn yíò gbọ́ran sí Mọ́ríátọ́nì lẹ́nu tíi nwọn ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ àti pé báyĩ òun yíò ní àwọn ibi apá ilẹ̀ nã ní ìní, èyítí yíò jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ nlá lãrín àwọn ènìyàn Nífáì, bẹ̃ni, ìṣẹ̀lẹ̀ èyítí yíò yọrísí sísọ òmìnira nwọn nù. Nítorínã Mórónì rán ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan lọ, pẹ̀lú àgọ́ nwọn, sí iwájú àwọn ènìyàn Mọ́ríátọ́nì, láti dènà nwọn lọ́wọ́ sísálọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá. O sì ṣe pé nwọn kò bọ́ síwájú nwọn àfi ìgbàtí nwọ́n dé etí ilẹ̀ Ibi-Ahoro; ibẹ̀ sì ni nwọ́n ti ṣíwájú nwọn, ní ibi ọ̀nà tọ́ró èyítí ó kọjá ní ẹ̀gbẹ́ òkun sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá, bẹ̃ni, ní ẹ̀gbẹ́ òkun, ní apá ìwọ̀-oòrùn àti ní apá ìlà-oòrun. O sì ṣe tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun nã èyítí Mórónì rán, èyítí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ í ṣe Tíákúmì darí rẹ̀, bá àwọn ènìyàn Mọ́ríátọ́nì; àwọn ènìyàn Mọ́ríátọ́nì sì jẹ́ ọlọ́kàn líle ènìyàn, (nítorítí nwọn ngba àtìlẹhìn nípa ti ìwà búburú rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀) tí ìjà sì bẹ́ sílẹ̀ lãrín nwọn, nínú èyítí Tíákúmì pa Mọ́ríátọ́nì tí ó sì ṣẹ́gun àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, tí ó sì kó nwọn lẹ́rú, tí ó sì padà sí àgọ́ Mórónì. Báyĩ sì ni ọdún kẹrìnlélógún ti ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin. Báyĩ sì ni a ṣe mú àwọn ènìyàn Mọ́ríátọ́nì padà. Ní kété tí nwọ́n sì ti ṣe májẹ̀mú láti gbé ìgbé ayé àlãfíà ni a sì mú nwọn padà sí ilẹ̀ Mọ́ríátọ́nì, tí ìrẹ́pọ̀ sì wà lãrín nwọn àti àwọn ènìyàn Léhì; a sì mú àwọn nã padà sí órí àwọn ilẹ̀ nwọn. O sì ṣe ni ọdún kannã tí àwọn ènìyàn Nífáì rí àlãfíà gbà padà, tí Nífáìhà, onídàjọ́ àgbà kejì kú, ó sì jẹ́ ìtẹ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìdúróṣinṣin tí ó pé níwájú Ọlọ́run. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó ti kọ̀ fún Álmà láti gba àwọn àkọsílẹ̀ nnì àti àwọn ohun wọnnì èyítí Álmà àti àwọn bàbá rẹ̀ kà kún ohun mímọ́ jùlọ; nítorínã Álmà ti gbé nwọn lé ọwọ́ ọmọ rẹ̀, Hẹ́lámánì. Kíyèsĩ, ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã yan ọmọ Nífáìhà sí orí ìtẹ́ ìdájọ́, dípò bàbá rẹ̀; bẹ̃ni, nwọn yàn án gẹ́gẹ́bí adájọ́ àgbà àti olórí lé àwọn ènìyàn nã lórí, pẹ̀lú ìbúra àti ìlànà mímọ́ láti ṣe ìdájọ́ òdodo, àti láti pa àlãfíà àti òmìnira àwọn ènìyàn nã mọ́, àti láti fún nwọn ní àwọn ẹ̀tọ́ mímọ́ nwọn láti sin Olúwa Ọlọ́run nwọn, bẹ̃ni, láti ṣe àtìlẹhìn fún àti lati ja ìjà òmìnira ti Ọlọ́run rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, àti láti mú àwọn ènìyàn búburú wá sí àìṣègbè ní ìbámu pẹ̀lú ìwà búburú nwọn. Nísisìyí kíyèsĩ, orúkọ rẹ̀ ni í ṣe Pahoránì. Pahoránì sì wà lórí ìtẹ́ ìdájọ́ bàbá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìjọbarẹ̀ ní òpin ọdún kẹrìnlélógún, lórí àwọn ènìyàn Nífáì. 51 Àwọn-afọbajẹ nlépa láti yí òfin padà kí nwọ́n sì fi ọba jẹ—Pahoránì àti àwọn-ẹni-òmìnira rí àtìlẹhìn gbà pẹ̀lú ohùn àwọn ènìyàn nã—Mórónì fi ipá mú afọbajẹ láti dábọ́bò orílẹ̀-èdè nwọn, láìṣe èyí nwọn yíò pa nwọ́n—Amalikíà àti àwọn ará Lámánì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá tí a ti mọdisí—Tíákúmì lé àwọn ará Lámánì padà sẹ́hìn ó sì pa Amalikíà nínú àgọ́ rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 67 sí 66 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún karundinlọgbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, lẹ́hìn tí nwọ́n ti fi àlãfíà lélẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn Léhì àti àwọn ènìyàn Mọ́ríátọ́nì nípa ti ilẹ̀ nwọn, tí nwọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ ọdún karundinlọgbọ̀n pẹ̀lú àlãfíà; Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọn kò ní àlãfíà tí ó pé fún ọjọ́ pípẹ́ ní ilẹ̀ nã, nítorítí asọ̀ bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín àwọn ènìyàn nã nípa onídàjọ́ àgbà nã Pahoránì; nítorí kíyèsĩ, àwọn apá kan nínú àwọn ènìyàn nã fẹ́ kí nwọ́n yí díẹ̀ nínú òfin nã padà. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Pahoránì kò yìi padà kò sì gbà kí nwọ́n yí òfin nã padà; nítorínã, kò tétísílẹ̀ sí àwọn tí nwọ́n ti fi ìfẹ́ inú nwọn àti ìbẽrè nwọn hàn nípa yíyí òfin nã padà. Nítorínã, àwọn tí nwọ́n fẹ́ kí a yí òfin nã padà bínú síi, nwọ́n sì fẹ́ kí ó dẹ́kun láti jẹ́ onídàjọ́ àgbà lórí ilẹ̀ nã; nítorínã, àríyànjiyàn líle bẹ́ sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ nã, ṣùgbọ́n kò yọrí sí ìtàjẹ̀sílẹ̀. Ó sì ṣe pé àwọn tí ó fẹ́ kí a rọ Pahoránì sílẹ̀ lórí ìtẹ́ ìdájọ́ ni à npè ní àwọn-afọbajẹ, nítorítí nwọ́n fẹ́ láti yí òfin padà ní ọ̀nà tí nwọn yíò fi da ìjọba olómìnira rú tí nwọn yíò sì fi ọba sí órí ilẹ̀ nã. Àwọn t í nwọ́n s ì fẹ́ kí Pahoránì wà síbẹ̀ gẹ́gẹ́bí onídàjọ́ àgbà lórí ilẹ̀ nã gba orúkọ àwọn-ẹni-òmìnira lé ara nwọn; báyĩ sì ni ìyapa wà lãrín nwọn, nítorítí àwọn ẹni-òmìnira nã ti pinnu tàbí pé nwọ́n dá májẹ̀mú láti gbé àwọn ẹ̀tọ́ àti ànfàní ìgbàgbọ́ nwọn ró ní ti ìjọba olómìnira. Ó sì ṣe tí nwọ́n parí ọ̀rọ̀ asọ̀ tí ó wà lãrín nwọn nípa ohùn àwọn ènìyàn nã. Ó sì ṣe tí ohùn àwọn ènìyàn nã gbe àwọn ẹni-òmìnira, Pahoránì sì di ìtẹ́ ìdájọ́ mú, èyítí ó fa àjọyọ̀ púpọ́ lãrín àwọn arákùnrin Pahoránì àti pẹ̀lú púpọ̀ nínú àwọn ẹniòmìnira, tí nwọ́n sì pa àwọnafọbajẹ lẹ́nu mọ́, tí nwọn kò sì tó láti dãbá láti ṣe àtakò ṣùgbọ́n tí nwọn kò ṣaláì gbé ipa ti òmìnira ró. Nísisìyí àwọn tí nfẹ́ kí ọba ó wa jẹ́ àwọn tí nwọn jẹ́ ìran olówó, nwọ́n sì nwá ọ̀nà láti jẹ́ ọba; nwọ́n sì rí àtìlẹhìn lọ́wọ́ àwọn tí nwá agbára àti àṣẹ lórí àwọn ènìyàn nã. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àsìkò yĩ jẹ́ èyítí ó léwu kí asọ̀ ó wà lãrín àwọn ènìyàn Nífáì; nítorí kíyèsĩ, Amalikíà ti rú ọkàn àwọn ènìyàn Lámánì sókè sí àwọn ènìyàn Nífáì, tí ó sì nkó àwọn ọmọ ogun jọ láti gbogbo ẹ̀ka ilẹ rẹ, ti o si ndi ìhámọ́ra fún nwọn, tí ó sì nṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogunpẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀; nítorítí ó ti búra láti mu ẹ̀jẹ̀ Mórónì. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwa ó ríi pé ìlérí rẹ̀ tí ó ṣe jẹ́ èyítí ó ṣe láì-farabalẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó ṣe ìmúrasílẹ̀ ara rẹ̀ àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ láti jáde wá láti jagun pẹ̀lú àwọn ara Nífáì. Nísisìyí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ kò pọ̀ tó ti àtẹ̀hìnwá, nítorí ti àwọn ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̃gbẹ̀rún tí nwọ́n pa nípasẹ̀ ọwọ́ àwọn ará Nífáì; ṣùgbọ́n l’áìṣírò àdánù nlá nwọ́n sí, Amalikíà ti kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó lágbára kan jọ, tóbẹ̃ tí ẹ̀rù bã láti sọ̀kalẹ̀ wá sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Bẹ̃ni, Amalikíà pãpã fúnrarẹ̀ sọ̀kalẹ̀ wá, níwájú àwọn ará Lámánì. Èyí sì jẹ́ ọdún karundinlọgbòn nínú ìjọba àwọn onídàjọ́; ó sì jẹ́ àkokò kannã tí nwọ́n ti bẹ̀rẹ̀sí parí ọ̀rọ̀ asọ̀ tí ó wà lãrín nwọn nípa ti onídàjọ́ àgbà, tĩ ṣe Pahoránì. Ó sì ṣe pé nígbàtí àwọn tí nwọn npè ní àwọn-afọbajẹ ti gbọ́ wípé àwọn ará Lámánì nbọ̀wá láti bá nwọn jagun, nwọ́n yọ̀ nínú ọkàn nwọn; nwọ́n sì kọ̀ láti gbé ohun ìjà ogun, nítorítí nwọ́n bínú gidigidi sí onídàjọ́ àgbà, àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn olómìnira nã, tí nwọ́n kọ̀ láti gbé ohun ìjà láti dãbò bò orílẹ̀-èdè nwọn. Ó sì ṣe pé nígbàtí Mórónì rí èyí, tí ó sì ríi pé àwọn ará Lámánì nbọ̀wá sínú etí ilẹ̀ nã, ó bínú gidigidi nítorí ọkàn líle àwọn ènìyàn nã tí òun ti ṣapá pẹ̀lú ìtẹramọ́ tí ó pọ̀ láti pa nwọ́n mọ́; bẹ̃ni, ó bínú púpọ̀-púpọ̀; ọkàn rẹ̀ kún fún ìrunú sí nwọn. Ó sì ṣe tí ó fi ẹ̀bẹ̀ ránṣẹ́ sí bãlẹ̀ ilẹ̀ nã, ní ìbámu pẹ̀lú ohùn àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n sì fẹ́ kí ó kã, kí ó sì fún un (Mórónì) ní agbára láti mú àwọn olùyapa nnì dãbò bò orílẹ̀ èdè nwọn, tàbí kí ó pa nwọn. Nítorítí ó jẹ́ ohun àníyàn àkọ́kọ́ fún un láti mú wá sí ópin àwọn ìjà àti àwọn ìyapa lãrín àwọn ènìyàn nã; nítorítí kíyèsĩ, èyí ni ó ti jẹ́ ìdí gbogbo ìparun nwọn láti àtẹ̀hìnwá. Ó sì ṣe tí olórí ilẹ̀ nã fi fún nwọn ní ìbámu pẹ̀lú ohùn àwọn ènìyàn nã. Ó sì ṣe tí Mórónì pàṣẹ pé kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ kí ó lọ kọlũ àwọn afọbajẹ, láti mú ìgbéraga àti ìwà ìjọra-ẹni-lójú nwọn kúrò, kí nwọ́n sì pa nwọ́n, bíkòjẹ́ bẹ̃, kí nwọ́n gbé ohun ìjà nwọn kí nwọ́n sì ṣe àtìlẹhìn fún ìjà òmìnira nã. Ó sì ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nã kọjá lọ ní ìkọlù nwọ́n; tí nwọ́n sì mú ìgbéraga àti ìwà ìjọra-ẹni-lójú nwọn kúrò, tó bẹ̃ tí ó fi jẹ́ wípé bí nwọ́n ṣe ngbé àwọn ohun ìjà-ogun nwọn sókè láti bá àwọn ènìyàn Mórónì jà ni nwọ́n nké nwọn lulẹ̀ tí nwọ́n sì rẹ́ nwọn mọ́lẹ̀. Ó sì ṣe tí iye àwọn olùyapa nnì tí nwọ́n fi idà ké lulẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin; àwọn olórí nwọn tí nwọn kò pa lójú ogun ni nwọ́n sì mú tí nwọ́n jù sínú tũbú, nítorítí kò sí àyè fún ìdájọ́ nwọn ní àkokò yìi. Àwọn olùyapa tí ó sì ṣẹ́kù nnì, jọ̀wọ́ ara nwọn fún gbígbé àsíá òmìnira nã ró, kàkà kí nwọn ó di kíké lulẹ̀ lọ́wọ́ idà, nwọ́n sì mú nwọn gbé àsíá ọ̀mìnira sókè lórí àwọn ilé ìṣọ́ gíga nwọn, àti nínú àwọn ìlú-nlá nwọn, àti látigbé ohun ìjà ogun fún ìdãbò bò orílẹ̀-èdè nwọn. Báyĩ sì ni Mórónì fi òpin sí àwọn afọbajẹ nnì, tí kò sì sí ẹnìkẹni tí a nfi orúkọ afọbajẹ pè mọ́; báyĩ sì ni ó fi òpin sí ìwà ipá àti ìgbéraga àwọn ènìyàn nnì tí nwọn nhu ìwà ìjọra-ẹni-lójú, ṣùgbọ́n a rẹ̀ nwọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin nwọn, àti láti jà takuntakun fún òmìnira nwọn kúrò nínú oko-ẹrú. Kíyèsĩ, ó sì ṣe pé bí Mórónì ṣe nfi òpin sí àwọn ogun àti asọ̀ lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀, tí ó sì nmú nwọn sínú àlãfíà àti ọ̀làjú, tí ó sì nṣe ìlànà fún ìmúrasílẹ̀ fún ogun pẹ̀lú àwọn ará Lámánì, kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì ti wọ inú ilẹ̀ Mórónì wá, èyítí nbẹ ní ibi ìhà etí òkun. Ó sì ṣe tí àwọn ará Nífáì kò lágbára tó nínú ìlú-nlá Mórónì; nítorínã, Amalikíà lé nwọn, ó sì pa púpọ̀. Ó sì ṣe tí Amalikíà mú ìlú-nlá nã ní ìní, bẹ̃ni, ó mú gbogbo àwọn ibi odi nwọn. Àwọn tí nwọ́n sì sá jáde kúrò ní inú ìlú nlá Mórónì lọ sínú ìlú nlá Nífáìhà; àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìlú-nlá Léhì kó ara nwọn jọ, nwọ́n sì ṣe ìmúrasílẹ̀ nwọ́n sì ṣetán láti bá àwọn ará Lámánì jagun. Ṣùgbọ́n ó ṣe tí Amalikíà kò gbà kí àwọn ará Lámánì ó lọ kọlũ ìlú-nlá Nífáìhà nínú ogun, ṣùgbọ́n ó mú nwọn dúró ní etí bèbè òkun, ó sì fi àwọn ènìyàn sí gbogbo ìlú-nlá láti pãmọ́ àti láti dãbò bò ó. Báyĩ ni ó sì tẹ̀síwájú, tí ó nmú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá, ìlú-nlá Nífáìhà, àti ìlú-nlá Léhì, àti ìlú-nlá Mọ́ríátọ́nì, àti ìlú-nlá Òmnérì, àti ìlú-nlá Gídì, àti ìlú-nlá Múlẹ́kì, gbogbo nwọn ni ó wà ní ibi ìhà ìlà-oòrùn ní ẹ̀gbẹ́ bèbè òkun. Báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì ṣe ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlúnlá, nípasẹ̀ ọgbọ́n àrékérekè Amalikíà, nípasẹ̀ àìmọye àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn, gbogbo nwọn ni nwọ́n sì dãbò bò ní ọ̀nà ìmọdisí ti Mórónì; gbogbo nwọn ni ó sì jẹ́ ibi-ìsádi fún àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí nwọ́n kọjá lọ sí etí ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, tí nwọ́n lé àwọn ará Nífáì níwájú nwọn tí nwọ́n sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí Tíákúmì pàdé nwọn, ẹnití ó pa Mọ́ríátọ́nì tí ó sì ti ṣíwájú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní sísá tí ó nsálọ. Ó sì ṣe tí ó ṣíwájú Amalikíà pẹ̀lú, bí ó ṣe nkó àwọn ẹgbẹ́-ọmọ ogun rẹ̀ púpọ̀ nnì kọjá lọ kí ó lè mú ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀ ní ìní, àti ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ ó bá ìjákulẹ̀ pàdé nítorípé Tíákúmì àti àwọn ará rẹ̀ lée padà, nítorípé ajagun nlá ni nwọn í ṣe; nítorípé gbogbo ọmọ ogun Tíákúmì ni ó tayọ àwọn ará Lámánì nínú agbára nwọn àti nínú ọgbọ́n ogun jíjà nwọn, tóbẹ̃ tí nwọ́n sì borí àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí nwọ́n yọ nwọ́n lẹ́nu, tóbẹ̃ tí nwọ́n sì pa nwọ́n àní títí ilẹ̀ fi ṣú. Ó sì ṣe tí Tíákúmì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pàgọ́ nwọn sí ibi etí ãlà ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀; tí Amalikíà sì pàgọ́ rẹ̀ sí ibi etí ãlà ilẹ̀ ní bèbè ẹ̀gbẹ́ òkun, báyĩ sì ni nwọ́n ṣe lé nwọn. Ó sì ṣe nígbàtí ó ti di alẹ́, Tíákúmì àti ìránṣẹ́ rẹ̀ yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́jáde nwọ́n sì jáde lọ ní alẹ́, nwọ́n sì lọ sínú ibùdó Amalikíà; sì kíyèsĩ, orun ti mú nwọn nítorítí ãrẹ̀ ṣe nwọ́n lọ́pọ̀, èyítí ó jẹ́ bẹ̃ nítorí lãlã tí nwọ́n ti ṣe lọ́jọ́ nã àti nítorí ọ́ru tí ó mú. Ó sì ṣe tí Tíákúmì yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ wọ inú àgọ́ ọba lọ, ó sì gún un ní ọ̀kọ̀ wọ inú àyà rẹ̀ lọ; ó sì pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láìjí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó sì tún yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ padà lọ sínú àgọ́ tirẹ̀, sì kíyèsĩ, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nsùn, ó sì jí nwọn, ó sì sọ gbogbo ohun tí òun ti ṣe. Ó sì mú kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ dúró ní ìmúrasílẹ̀, bóyá àwọn ará Lámánì lè jí kí nwọ́n sì wá láti kọlũ nwọ́n. Báyĩ sì ni ọdún karundinlọgbọ̀n ti ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí; báyĩ nã sì ni ọjọ́ ayé Amalikíà parí. 52 Ámmórọ́nì rọ́pò Amalikíà gẹ́gẹ́bí ọba àwọn ará Lámánì—Mórónì, Tíákúmì, àti Léhì ṣíwájú àwọn ará Nífáì nínú ogun àjàṣẹ́gun pẹ̀lú àwọn ará Lámánì—Nwọ́n tún ìlú-nlá Múlẹ́kì mú, nwọ́n sì pa Jákọ́bù ará Sórámù. Ní ìwọ̀n ọdún 66 sí 64 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ó sì ṣe ní ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, ẹ kíyèsĩ, nígbàtí àwọn ará Lámánì jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kíni ní oṣù kíni, ẹ kíyèsĩ, nwọ́n rí Amalikíà tí ó ti kú nínú àgọ́ rẹ̀; nwọ́n sì ríi pẹ̀lú pé Tíákúmì ṣetán láti bá nwọn jagun ní ọjọ́ nã. Àti nísisìyí, nígbàtí àwọn ará Lámánì rí èyí ẹ̀rù bà nwọ́n; nwọ́n sì pa èrò nwọn láti kọjá lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà lápá àríwá tí nwọ́n sì padà sẹ́hìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun nwọn sínú ìlú-nlá Múlẹ́kì, nwọ́n sì bọ́ sínú ãbò àwọn ìmọdisí nwọn. Ó sì ṣe tí nwọ́n yan arákùnrin Amalikíà lọ́ba sórí àwọn ènìyàn nã; orúkọ rẹ̀ sì ni Ámmórọ́nì, báyĩ ni ọba Ámmórọ́nì tí í ṣe arákùnrin ọba Amalikíà, di yíyàn láti jọba rọ́pò rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó pàṣẹ pé kí àwọn ènìyàn rẹ fọwọ́mú àwọn ìlú-nlá nnì, èyítí nwọ́n ti mú nípa ìtàjẹ̀sílẹ̀; nítorítí nwọn kò mú ìlú-nlá kankan bíkòbájẹ́wípé nwọ́n ta ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ sílẹ̀. Àti nísisìyí, Tíákúmì ríi pé àwọn ará Lámánì ṣetán láti fọwọ́mú àwọn ìlú-nlá tí nwọ́n ti mú, àti àwọn apá ilẹ̀ nã tí nwọ́n ti ní ní ìní; àti pẹ̀lú nígbàtí ó ríi bí nwọ́n ti pọ̀ tó, Tíákúmì wòye pé kò jẹ́ ohun tí ó tọ́ pé kí òun gbìdánwò láti kọlũ nwọ́n nínú àwọn ibi ìsádi nwọn. Ṣùgbọ́n ó fi àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pamọ́ yíká kiri, bí ẹnití ó nmúrasílẹ̀ fún ogun; bẹ̃ni, àti nítọ́tọ́ ó nṣe ìmúrasílẹ̀ láti dãbò bò ara rẹ̀ lọ́wọ́ nwọn, nípa mímọ́ àwọn ògiri yíká tí ó sì npèsè àwọn ibi ìsádi. Ó sì ṣe tí ó nṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun báyĩ títí di ìgbà tí Mórónì fi fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ láti fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ní ágbára. Mórónì sì tún ránṣẹ́ síi pé kí ó dá gbogbo àwọn òndè tí ó ṣubú lọ́wọ́ sĩ dúró; nítorítí bí àwọn ará Lámánì ṣe ti mú àwọn ondè púpọ̀, pé kí ó dá gbogboàwọn òndè àwọn ará Lámánì dúró fún ìdásílẹ̀ fún àwọn ẹnití àwọn ará Lámánì ti mú. Ó sì tún ránṣẹ́ síi pé kí ó dãbò bò ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀ nnì, kí ó sì dãbò bò ọ̀nà tọ́ró nnì èyítí ó wọ inú ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà àríwá, kí àwọn ará Lámánì má lè gba ilẹ̀ nã kí nwọ́n sì lágbára láti dà nwọ́n lãmu ní gbogbo ìhà. Mórónì sì ránṣẹ́ síi, pé kí ó ṣe òtítọ́ láti dí agbègbè ilẹ̀ nnì mú, àti pé òun yíò wá gbogbo ọ̀nà láti nà àwọn ará Lámánì tí ó wà ní agbègbè ibẹ̀, bí agbára òun ti tó, pé bóyá òun lè tún gba àwọn ìlú-nlá nnì tí nwọ́n ti gbà lọ́wọ́ nwọn tẹ́lẹ̀ padà; nípa ọgbọ́n ẹ̀tàn tàbí ní ọ̀nà míràn àti pé òun yíò kọ́ ìmọdisí àti fi agbára fún àwọn ìlú-nlá tí ó wà ní àyíká, àwọn tí nwọn kò tĩ bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Lámánì. Ó sì tún sọ fún un pé, èmi yíò tọ̣́ wa, ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì ti kọlũ wá ní ìhà ibi ãlà ilẹ̀ tí ó wà ní apá ibi òkun apá ìwọ̀-ọ́rùn; sì kíyèsĩ, mo lọ láti kọlũ nwọ́n, nítoriã ni èmi kò ṣe lè tọ̣́ wa. Nísisìyí, ọba nã (Ámmórọ́nì) ti jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ó sì ti wí fún ayaba nípa ikú arákùnrin rẹ̀, ó sì ti kó àwọn ọmọ ogun púpọ̀ jọ, tí nwọ́n sì jáde lọ, láti dojúkọ àwọn ará Nífáì ní ibi ãlà ilẹ̀ nã tí ó wà ní ẹgbẹ́ òkun apá ìwọ oòrùn. Báyĩ ni ó sì nlépa láti dãmú àwọn ará Nífáì, àti láti fa nínú àwọn ọmọ ogun nwọn sínú apá ilẹ̀ nnì, bí ó tilẹ̀jẹ́pé ó ti pàṣẹ pé kí àwọn tí ó fi sẹ́hìn ó mú àwọn ìlú-nlá nã ní ìní, pé kí àwọn nã ó dãmú àwọn ará Nífáì tí nwọ́n wà ní ibi ãlà ilẹ̀ tí ó wà ní ẹgbẹ́ òkun apá ilà oòrùn, àti pé kí nwọ́n mú àwọn ilẹ̀ nwọn ní ìní bí agbára nwọn bá ti tó, gẹ́gẹ́bí agbára àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn. Báyĩ sì ni àwọn ará Nífáì wà nínú ipò ewu ní òpin ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ó sì ṣe ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, ni Tíákúmì, nípa àṣẹ Mórónì—ẹnití ó ti kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun jọ láti dãbò bò àwọn ãlà ilẹ̀ tí ó wà ní apá gúsù àti apá ìwọ oòrùn ilẹ̀ nã, tí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá lọ sí apá ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, láti lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún Tíákúmì pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti gba àwọn ìlú-nlá tí nwọ́n ti pàdánù tẹ́lẹ̀— Ó sì ṣe tí Tíákúmì ti gba àṣẹ láti lọ kọlũ ìlú-nlá Múlẹ́kì, kí ó sì gbã padà bí ó bá ṣeéṣe. Ó sì ṣe tí Tíákúmì ṣe ìmúrasílẹ̀ láti lọ kọlũ ìlú-nlá Múlẹ́kì, kí ó sì kọjá lọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ láti kọlu àwọn ará Lámánì; ṣùgbọ́n ó ríi pé kò ṣeéṣe fún òun láti borí nwọn nígbàtí nwọ́n wà nínú àwọn ibi ìsádi nwọn; nítorínã ó pa èrò wọ̀nyí tì, ó sì tún padà lọ sínú ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀, láti dúró de bíbọ̀wá Mórónì, láti lè gba agbára kún ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. Ó sì ṣe tí Mórónì dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sínú ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, ní òpin ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kéjìdínlọ́gbọ̀n ni Mórónì àti Tíákúmì àti púpọ̀ nínú àwọn olórí ológun sì níàjọròpọ̀ nípa ti ogun—nípa ohun tí nwọn yíò ṣe láti mú àwọn ará Lámánì jáde wá bá nwọn jagun; tàbí pé kí nwọ́n wá ọ̀nà láti tàn nwọ́n jáde kúrò nínú àwọn ibi ìsádi nwọn, kí nwọ́n lè borí nwọ́n kí nwọn sì gba ìlú-nlá Múlẹ́kì padà. Ó sì ṣe tí nwọ́n rán àwọn oníṣẹ́ sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, tí ó ndãbò bò ìlú-nlá Múlẹ́kì, sí olórí nwọn, ẹnití orúkọ rẹ̀ í ṣe Jákọ́bù, pé nwọn fẹ́ kí ó jáde wá pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ láti pàdé nwọn lórí ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó wà lãrín àwọn ìlú nlá méjẽjì. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Jákọ́bù, ẹnití í ṣe ará Sórámù, kọ̀ láti tọ̀ nwọ́n wá pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ lórí ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí Mórónì nítorí kò ní ìrètí láti pàdé nwọn lórí ilẹ̀ tí ó dọ́gba, nítorínã, ó gbèrò láti tan àwọn ará Lámánì nã jáde nínú àwọn ibi ìsádi nwọn. Nítorínã, ó mú kí Tíákúmì kó àwọn ọmọ ogun díẹ̀ kí nwọn sì kọjá lọ sí ẹ̀gbẹ́ bèbè òkun; Mórónì àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, ní àṣálẹ́, sì kọjá lọ sínú aginjù, ní apá ìwọ̀-oòrùn ìlú-nlá Múlẹ́kì; báyĩ nã, ní ọjọ́ kejì, nígbàtí àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn ará Lámánì rí Tíákúmì, nwọ́n sá nwọ́n sì sọọ́ fún Jákọ́bù, olórí nwọn. Ó sì ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì kọjá lọ ní ìkọlu Tíákúmì, tí nwọ́n rò wípé nípa pípọ̀ nwọn àwọn yíò borí Tíákúmì nítorípé nwọn kò pọ̀. Bí Tíákúmì sì ti rí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì tí nwọ́n nbọ̀wá dojúkọ òun ni ó bẹ̀rẹ̀sí sá padà lọ sí ẹ̀gbẹ́ bèbè òkun, sí apá àríwá. Ó sì ṣe nígbàtí àwọn arà Lámánì ríi pé ó nsá padà, nwọ́n ní ìgboyà nwọ́n sì sá tẹ̀lé nwọn pẹ̀lú agbára. Bí Tíákúmì sì ṣe ndarí àwọn ará Lámanì nã lọ tí nwọn nsá tẹ̀lée lásán, ẹ kíyèsĩ Mórónì pàṣẹ pé kí apá kan nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá lọ sínú ìlú-nlá nã, kí nwọn ó sì múu ní ìní. Báyĩ sì ni nwọ́n ṣe, tí nwọ́n sì pa gbogbo àwọn tí nwọ́n fi sílẹ̀ láti dãbò bò ìlú-nlá nã, bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí nwọn kọ̀ láti jọ̀wọ́ àwọn ohun-ìjà ogun nwọn. Báyĩ sì ni Mórónì ṣe gba ìlú-nlá Múlẹ́kì pẹ̀lú apá kan nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, tí ó sì kọjá lọ pẹ̀lú àwọn tí ó kù láti dojúkọ àwọn ará Lámánì nígbàtí nwọ́n padà bọ̀wá ní lílé tí nwọ́n lé Tíákúmì lọ. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì lé Tíákúmì títí nwọ́n fi dé ẹ̀gbẹ́ ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀, tí Léhì àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun kékeré kan tí nwọ́n ti fi sílẹ̀ láti dãbò bò ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀, sì pàdé nwọn. Àti nísisìyí sì kíyèsĩ, nígbàtí àwọn olórí ológun àwọn ará Lámánì rí Léhì pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ tí nwọn nbọ̀ láti dojúkọ nwọ́n, nwọ́n sá nínú ìdàmú tí ó pọ̀, fún ìbẹ̀rù pé nwọn kò ní lè mú ìlú-nlá Múlẹ́kì kí Léhì tó lé nwọn bá; nítorítí ó ti rẹ̀ nwọ́n nítorí ìrìnàjò nwọn, tí àwọn ọmọ ogun Léhì ṣì lágbára. Nísisìyí àwọn ará Lámánì kò mọ̀ pé Mórónì ti dé ẹ̀hìn nwọn pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀; tí ó sì jẹ́ wípé ẹ̀rù Léhì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nìkan ni ó nbá nwọ́n. Nísisìyí Léhì kò ní ìfẹ́ láti lé nwọn bá títí nwọn ó fi pàdé Mórónì àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. Ó sì ṣe pé kí àwọn ará Lámánì tó sá padà tán ni àwọn ará Nífáì yí nwọn ká, àwọn ọmọ ogun Mórónì ní apá kan, àti àwọn ọmọ ogun Léhì ní apá kejì, tí gbogbo nwọn sì wà nínú àkọ̀tun agbára tí ó péye; ṣùgbọ́n àwọn ará Lámánì ti di alãrẹ̀ nítorí ti ìrìn àjò nwọn. Mórónì sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti kọlũ nwọ́n títí nwọn ó fi kó àwọn ohun ìjà ogun nwọn sílẹ̀. Ó sì ṣe tí Jákọ́bù, ẹnití í ṣe olórí nwọn tí í ṣe ará Sórámù, tí ó sì tún ní ẹ̀mí akíkanjú, tí ó ṣãjú àwọn ará Lámánì lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrunú sí Mórónì. Nítorípé Mórónì sì wà lójú ọ̀nà nwọn, nítorínã ni Jákọ́bù ṣe pinnu láti pa òun pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kí ó sì la ãrín kọjá lọ si ìlú-nlá Múlẹ́kì. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Mórónì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lágbára jù nwọ́n lọ; nítorínã nwọn kò fà sẹ́hìn níwájú àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí nwọ́n jà ní apá méjẽjì pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìrunú; tí a pa púpọ̀ ní apá méjẽjì; bẹ̃ni, tí Mórónì sì fara gbọgbẹ́ tí a sì pa Jákọ́bù. Léhì sì tẹ̀ síwájú látẹ̀hìn pẹ̀lú ìrunú púpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ alágbára, tí àwọn ará Lámánì tí ó wà lẹ́hìn sì kó ohun ìjà ogun nwọn lélẹ̀; tí àwọn tí ó kù nínú nwọn, nítorítí ìdãmú púpọ̀ bá nwọn, kò sì mọ́ ibití nwọn yíò lọ tàbí ibití nwọn yíò kọlù. Nísisìyí nígbàtí Mórónì rí ìdãmú nwọn, ó wí fún nwọn pé: Bí ẹ̀yin yíò bá kó ohun ìjà ogun nyín wá kí ẹ sì jọ̀wọ́ nwọn sílẹ̀, ẹ kíyèsĩ àwa yíò dáwọ́dúró nínú ìtàjẹ̀ nyín sílẹ̀. Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Lámánì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àwọn olórí ọmọ ogun nwọn, gbogbo àwọn tí a kò pa, jáde wá nwọ́n sì kó àwọn ohun ìjà ogun nwọn sílẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ Mórónì, tí nwọ́n sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun nwọn láti ṣe bákannã. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn tí kò ṣe báyĩ pọ̀; àwọn tí kò sì kó idà nwọn lélẹ̀ ni a mú tí a sì dè, a sì gba àwọn ohun ìjà ogun nwọn lọ́wọ́ nwọn, a sì mú kí nwọn kọjá lọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn sínú ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀. Àti nísisìyí iye àwọn tí nwọn kó lẹ́rú pọ̀ púpọ̀ ju iye àwọn tí a pa, bẹ̃ni, ju iye àwọn tí a ti pa ní apá méjẽjì. 53 Àwọn ará Lámánì tí nwọn kó lẹ́rú ni nwọ́n lò láti mọ́ odi yí ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀—Àwọn ìyapa lãrín àwọn ará Nífáì mú kí àwọn ará Lámánì ní ìṣẹ́gun—Hẹ́lámánì di olùdarí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹgbẹ̀rún méjì ti àwọn ènìyàn Ámọ́nì. Ní ìwọ̀n ọdún 64 sí 63 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí nwọ́n fi àwọn ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ àwọn ará Lámánì nã tí nwọ́n kó lẹ́rú, tí nwọ́n sì pã láṣẹ fún nwọn láti jáde lọ kí nwọ́n sì sin àwọn òkú ara nwọn, bẹ̃ni, àti pẹ̀lú àwọn òkú àwọn ará Nífáì tí a ti pa; Mórónì sì fi àwọn ènìyàn tì nwọ́n láti máa ṣọ́ nwọn bí nwọ́n ṣe nṣiṣẹ́ nwọn gbogbo. Mórónì sì lọ sí ìlú-nlá Múlẹ́kì pẹ̀lú Léhì, ó sì gba àkóso ìlú-nlá nã ó sì fi lé ọwọ́ Léhì. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, Léhì yí jẹ́ ẹnití ó ti wà pẹ̀lú Mórónì ní ìgbà púpọ̀ nínú àwọn ogun tí ó jà; ó sì jẹ́ ẹnìkan tí ó dàbí Mórónì, nwọ́n sì yọ̀ nínú ìwàlálãfíà àwọn ara nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n fẹ́ràn ara nwọn, gbogbo àwọn ènìyàn Nífáì ni ó sì fẹ́ràn nwọn. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí àwọn ará Lámánì ti sin àwọn ẹnití ó kú nínú àwọn ará wọn àti àwọn ará Nífáì tán, a dá nwọ́n padà lọ sínú ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀; tí Tíákúmì, nípa àṣẹ Mórónì, sì mú kí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣiṣẹ́ nípa gbígbẹ́ ọ̀gbun yí ilẹ̀ nã ká tàbí pé ìlú-nlá nnì, Ibi-Ọ̀pọ̀. Ó sì mú kí nwọn kọ́ ọgbà tí a fi igi rírẹ́ ṣe sí ọwọ́ inú ọ̀gbun nã; nwọn sì kó amọ̀ ti ọgbà nã èyítí nwọn fi igi rírẹ́ ṣe; báyĩ sì ni nwọ́n ṣe mú àwọn ará Lámánì nã ṣiṣẹ́ títí nwọ́n fi yí ìlú-nlá nnì Ibi-Ọ̀pọ̀ ká kiri pẹ̀lú odi tí ó lágbára tí nwọ́n mọ́ pẹ̀lú igi rírẹ́ àti amọ̀, tí ó sì ga sókè lọ́pọ̀lọpọ̀. Ìlú-nlá yí sì di ibi ìsádi láti ìgbà yí lọ títí; nínú ìlú-nlá yĩ ni nwọ́n sì ti nṣọ́ àwọn ará Lámánì tí nwọ́n kó lẹ́rú; bẹ̃ni, àní nínú odi tí nwọn ti mú kí nwọn ó kọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ara nwọn. Nísisìyí Mórónì níláti mú àwọn ará Lámánì ṣiṣẹ́, nítorípé ó rọrùn láti ṣọ́ nwọn bí nwọ́n bá nṣiṣẹ́; ó sì fẹ́ kí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ pé nígbàtí òun yíò bá kọlu àwọn ará Lámánì nã. Ó sì ṣe tí Mórónì nípa ṣíṣe báyĩ ní ìṣẹ́gun lórí ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì tí ó lágbára jùlọ, tí ó sì ti gba ìlú-nlá Múlẹ́kì, èyítí íṣe ọ̀kan nínú àwọn tí ó lágbára jùlọ nínú àwọn ìlú-nlá àwọn ará Lámánì nínú ilẹ̀ àwọn ará Nífáì; báyĩ nã ni a sì ṣe kọ́ ibi ìsádi pẹ̀lú láti kó àwọn ẹrú rẹ̀ sí. Ó sì ṣe tí kò lépa láti bá àwọn ará Lámánì jagun mọ́ nínú ọdún nã, ṣùgbọ́n ó mú kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ máa ṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun, bẹ̃ni, àti pé kí nwọn ó ṣe ìgbáradì sílẹ̀ de àwọn ará Lámánì, bẹ̃ni, àti lati gba àwọn obìnrin nwọn àti àwọn ọmọ nwọn lọ́wọ́ ìyàn àti ìpọ́njú, àti pípèsè oúnjẹ fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, ní ẹ̀gbẹ́ òkun tí ó wà ní apá ìwọ oòrùn, tí ó wà ní apá gúsù nígbàtí Mórónì kò sí lãrín nwọn, tí àwọn ará Nífáì kan sì dìtẹ̀, èyítí ó fa ìyapa lãrín nwọn, tí nwọ́n sì ti gbà nínú ilẹ̀ àwọn ará Nífáì, bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí nwọ́n ti gbà nínú àwọn ìlú-nlá nwọn tí ó wà ní apá ilẹ̀ nã. Báyĩ sì ni ó rí nítorí ti àìṣedẽdé tí ó wà lãrín nwọn, bẹ̃ni, nítorí ìyapa àti ọ̀tẹ̀ lãrín ara nwọn, nwọ́n bọ́ sínú ipò tí ó léwu púpọ̀ jùlọ. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, mo ní ohun kan tí èmi yíò sọ nípa àwọn ènìyàn Ámọ́nì, ní ìbẹ̀rẹ̀, ará Lámánì ni nwọn í ṣe; ṣùgbọ́n nípasẹ̀ Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, tàbí pé nípasẹ̀ agbára àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ti yí nwọn padà sí ọ́dọ̀ Olúwa; a sì ti mú nwọn wá sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí àwọn ará Nífáì sì ti ndãbò bò nwọ́n láti ìgbà nã. Àti nítorí ti májẹ̀mú nwọn, nwọ́n ti yẹra fún gbígbé ohunìjà-ogun ní ìdojúkọ àwọn arákùnrin nwọn; nítorítí nwọ́n ti dá májẹ̀mú pé àwọn kò ní tàjẹ̀sílẹ̀ mọ́ láé; àti pé ní ìbámu pẹ̀lú májẹ̀mú nwọn, nwọn iba ti parun; bẹ̃ni, nwọn iba ti gbà kí nwọ́n ṣubú sí ọ́wọ́ àwọn arákùnrin nwọn, bí kò bá ṣe ti ãnú àti ìfẹ́ nlá ti Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní fún nwọn. Nítorí ìdí èyí ni nwọ́n sì ṣe mú nwọn jáde wá sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; tí nwọ́n sì ti nrí ìdãbò bò àwọn ará Nífáì láti ìgbà nã. Ṣùgbọ́n ó ṣe nígbàtí nwọ́n rí ewu nã, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú àti wàhálà tí àwọn ará Nífáì faradà nítorí nwọn, ãnú ṣe nwọ́n, nwọ́n sì ní ìfẹ́ láti gbé ohun ìjà-ogun fún ìdãbò orílẹ̀-èdè nwọn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ní kété tí nwọn fẹ́ gbé àwọn ohun ìjà ogun nwọn, Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ yí nwọn lọ́kàn padà, nítorítí nwọn ṣetán láti sẹ́ májẹ̀mú tí nwọ́n ti dá. Hẹ́lámánì sì bẹ̀rù pé bí nwọ́n bá ṣe báyĩ nwọn yíò sọ ẹ̀mí nwọn nù; nítorínã gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ti dá májẹ̀mú yĩ ni nwọ́n níláti máa wo àwọn arákùnrin nwọn bí nwọ́n ṣe nla ipọ́njú wọn kojá, nínú ipò ewu tí nwọ́n wà ní àkokò yĩ. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ó sì ṣe tí nwọ́n ní àwọn ọmọkùnrin púpọ̀, tí nwọn kò tĩ dá májẹ̀mú nã pé àwọn kò ní gbé ohun ìjà-ogun láti dãbò bò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn; nítorínã nwọn kó ara nwọn jọ ní àkokò yĩ, gbogbo àwọn tí ó lè gbé ohun ìjà-ogun, nwọn sì pe ara nwọn ní ará Nífáì. Nwọ́n sì dá májẹ̀mú pé àwọn yíò jà fún òmìnira àwọn ará Nífáì, bẹ̃ni, láti dãbò bò ilẹ̀ nã, sí fifi ẹmí nwọn lelẹ; bẹ̃ni, àní nwọ́n dá májẹ̀mú pé àwọn kò ní jọ̀wọ́ òmìnira nwọn láéláé, ṣùgbọ́n àwọn yíò jà lórí ohun gbogbo láti dãbò bò àwọn ará Nífáì àti ara nwọn kúrò nínú oko-ẹrú. Nísisìyí kíyèsĩ, ẹgbẹ̀rún méjì ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin nnì í ṣe, tí nwọ́n dá májẹ̀mú yĩ tí nwọ́n sì gbé ohun ìjà-ogun nwọn láti dãbò bò orílẹ̀-èdè nwọn. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, bí ó ti jẹ́ wípé nwọ́n kò mú ídíwọ́ bá àwọn ará Nífáì látẹ̀hìnwá, nísisìyí nwọ́n tún jẹ́ olùrànlọ́wọ́ nlá ni àkókò yĩ; nítorítí nwọ́n gbé ohun ìjà-ogun nwọn, nwọ́n sì fẹ́ kí Hẹ́lámánì jẹ́ olórí nwọn. Ọ̀dọ́mọkùnrin sì ni gbogbo nwọn í ṣe nwọ́n sì jẹ́ akíkanjú nínú ìgboyà, àti nínú agbára àti ìṣe; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, eleyĩ nìkan kọ́—nwọ́n jẹ́ olọ́tọ́ ní gbogbo ìgbà nínú ohunkóhun tí nwọ́n bá fi lé nwọn lọ́wọ́. Bẹ̃ni, nwọ́n jẹ́ ẹni olótĩtọ́ àti aláìrékọjá, nítorítí a ti kọ́ nwọn láti pa òfin Ọlọ́run mọ́ àti láti máa rìn ní ìdúróṣinṣin níwájú rẹ̀. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Hẹ́lámánì lọ níwájú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún méjì rẹ̀, fún ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ó wà níbi ãlà ilẹ̀ tí ó wà ní apá gúsù ní ẹ̀gbẹ́ òkun apá ìwọ̀-oòrùn. Báyĩ sì ni ọdún kéjìdínlọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin. 54 Ámmórọ́nì àti Mórónì ṣe àdéhùn fún ṣíṣe pàṣípàrọ̀ àwọn ènìyàn nwọn tí nwọ́n kó lẹ́rú—Mórónì fẹ́ kí àwọn ará Lámánì kúrò lórí ilẹ̀ nwọn k í nwọ́n s ì dáwọ́ ìwà ìpànìyàn nwọn dúró—Ámmárọ́nì fẹ́ kí àwọn ará Nífáì kó àwọn ohun ìjà nwọn lélẹ̀ kí nwọ́n sì wà lábẹ́ àwọn ará Lámánì. Ní ìwọ̀n ọdún 63 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kọkàndínlọ́gbọ̀n àwọn onídàjọ́, tí Ámmórọ́nì ránṣẹ́ sí Mórónì pé òun fẹ́ kí ó ṣe pàṣípàrọ̀ àwọn ènìyàn nwọn tí nwọ́n kó lẹ́rú. Ó sì ṣe tí Mórónì ní inú dídùn púpọ̀púpọ̀ sí ìbẽrè yĩ, nítorítí ó fẹ́ àwọn oúnjẹ tí nwọn nlò fún ìtọ́jú àwọn ará Lámánì tí a kó lẹ́rú fún ìtọ́jú àwọn ènìyàn tirẹ̀; ó sì tún fẹ́ àwọn ènìyàn tirẹ̀ fún fífi agbára fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. Nísisìyí àwọn ará Lámánì ti mú àwọn obìnrin àti ọmọ púpọ̀, tí kò sì sí obìnrin kan tàbí ọmọ kan lãrín àwọn tí a kó lẹ́rú tí í ṣe ti Mórónì, tàbí àwọn ẹrú tí Mórónì ti mú; nítorínã Mórónì pinnu lọ́nà ọgbọ́n àrékérekè láti gbà nínú àwọn ará Nífáì tí nwọn kó lẹ́rú lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì bí ó ti ṣẽṣe tó. Nítorínã ó kọ ìwé, ó sì fi rán ìránṣẹ́ Ámmórọ́nì, ẹnití ó mú ìwé tọ Mórónì wá ní ìṣãjú. Nísisìyí àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí ó kọ ránṣẹ́ sí Ámmórọ́nì, wípé: Kíyèsĩ, Ámmórọ́nì, èmi kọ̀wé sí ọ nípa ti ogun yĩ tí ìwọ nbá àwọn ènìyàn mi jà, tàbí kí a wípé èyítí arákùnrin rẹ nbá wọn jà, àti tí ìwọ ṣì pinnu láti máa jàlọ lẹ́hìn ikú rẹ̀. Kíyèsĩ, èmí yíò sọ ohun kan fún ọ nípa àìṣègbè Ọlọ́run, àti idà ìbínú nlá rẹ̀, èyítí ó gbé sókè sí ọ àfi bí ìwọ bá ronúpìwàdà kí o sì kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ padà sínú ilẹ̀ rẹ, tàbí ilẹ̀ ìní rẹ, èyítí í ṣe ilẹ̀ Nífáì. Bẹ̃ni, èmi sọ àwọn ohun wọ̀nyí fún ọ bí ìwọ bá lè ṣe ìgbọràn sí nwọn; bẹ̃ni, èmi yíò sọ fún ọ nípa ọ̀run àpãdì búburú nnì tí ó ndúró láti tẹ́wọ́gba àwọn apànìyàn bí ìrẹ àti arákùnrin rẹ ti jẹ́, àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà tí ẹ sì dẹ́kun ète ìpànìyàn nyin gbogbo, kí ẹ sì padà pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nyín sínú ilẹ̀ nyín. Ṣùgbọ́n nítorípé ẹ̀yin ti kọ àwọn ohun wọ̀nyí nígbà kan rí, tí ẹ sì ti bá àwọn ènìyàn tí í ṣe ti Olúwa jà, bẹ̃gẹ́gẹ́ ni èmi nretí pé ẹ̀yin yíò tún ṣeé lẹ̃kan síi. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, àwa ti múrasílẹ̀ láti dojúkọ nyín; bẹ̃ni, àti pé àfi bí ẹ̀yin bá kọ ète nyín sílẹ̀, ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin yíò fa ìbínú Ọlọ́run nnì èyí tí ẹ̀yin ti kọ̀ sí órí nyín, àní títí dé ìparun nyín pátápátá. Ṣùgbọ́n, bí Olúwa ti wà lãyè, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa yíò kọlũ nyín àfi bí ẹ̀yin bá padà, láìpẹ́ ni a ó sì bẹ̀ yín wò pẹ̀lú ikú, nítorítí àwa yíò di àwọn ìlú-nlá wa àti àwọn ilẹ̀ wa mú; bẹ̃ni, àwa yíò sì gbé ẹ̀sìn wa ró àti ipa ọ̀nà ìfẹ́ Ọlọ́run wa. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, mo lérò wípé èmi nbá nyín sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lásán ni; tàbí pé mo lérò wípé ọmọ ọ̀run àpãdì ni ìwọ í ṣe; nítorínã èmi yíò parí ìwé mi nípa sísọ fún ọ pé èmi kò ní ṣepàṣípàrọ̀ àwọn ènìyàn tí a kó lẹ́rú, àfi bí ẹ̀yin yíò bá jọ̀wọ́ ọkùnrin kan àti ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, fún ẹyọ ẹnìkan tí a mú lẹ́rú; bí ẹ̀yin yíò bá ṣe èyí, èmi yíò ṣe pàṣípàrọ̀. Àti kíyèsĩ, bí ẹ̀yin kò bá ṣe eleyĩ, èmi yíò kọlù nyín pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi; bẹ̃ni, àní èmi yíò di ìhámọ́ra ogun fún àwọn obìnrin àti ọmọdé mi, èmi yíò sì kọlu nyín, èmi yíò sì tẹ̀lé nyin àní wọ inú ilẹ̀ ara nyín, èyítí í ṣe ilẹ̀ ìní wa àkọ́kọ́; bẹ̃ni, yíò sì jẹ́ ẹ̀jẹ̀ fún ẹ̀jẹ̀, bẹ̃ni, ẹ̀mí fún ẹ̀mí; èmi yíò sì gbógun tì nyín àní títí a ó fi pa nyín run kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Kíyèsĩ, mo wà nínú ìbínú mi, àti àwọn ènìyàn mi pẹ̀lú; ẹ̀yin ti wá ọ̀nà láti pa wá, àwa sì wá ọ̀nà láti dãbò bò ara wa. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, bí ẹ̀yin bá lépa síi láti pa wá run àwa yíò lépa láti pa nyín run; bẹ̃ni, àwa yíò sì lépa láti gba ilẹ̀ wa, ilẹ̀ ìní wa àkọ́kọ́. Nísisìyí mo parí ìwé mi. Èmi ni Mórónì, tí í ṣe olórí àwọn ènìyàn ará Nífáì. Nísisìyí ó sì ṣe tí Ámmórọ́nì, lẹ́hìn tí ó ti gba ìwé yĩ, ó bínú; ó sì kọ ìwé míràn ránṣẹ́ sí Mórónì, àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kọ, tí ó wípé: Èmi ni Ámmórọ́nì, ọba àwọn ará Lámánì; èmi ni arákùnrin Amalikíà ẹnití ẹ̀yin ti pa. Kíyèsĩ, èmi yíò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lára nyín, bẹ̃ni, èmi yíò sì kọ lù nyín pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi, nítorítí èmi kò bẹ̀rù àwọn ẽmí ìkìlọ̀ rẹ. Nítorí ẹ kíyèsĩ, àwọn bàbá nyín ṣẹ àwọn arákùnrin nwọn, tóbẹ̃ tí nwọ́n jà nwọ́n lólè ẹ̀tọ́ nwọn sí ìjọba nígbàtí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ nwọn. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin yíò bá kó àwọn ohun ìjà ogun nyín lélẹ̀, kí ẹ sì jọ̀wọ́ ara nyín fún àwọn tí ó tọ́ sí láti ṣe ìjọba lée nyín lórí, nígbànã ni èmi yíò mú kí àwọn ènìyàn mi kó àwọn ohun ìjà ogun nwọn lélẹ̀ tí nwọn kò sì ní bá nyín jagun mọ́. Kíyèsĩ, ìwọ ti mí ẽmí ìkìlọ̀ púpọ̀ sí èmi àti àwọn ènìyàn mi; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwa kò bẹ̀rù àwọn ẽmí ìkìlọ̀ rẹ. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi yíò gbà láti ṣe pàṣípàrọ̀ àwọn tí a kó lẹ́rú gẹ́gẹ́bí ó ti bẽrè, tayọ̀tayọ̀, kí èmi ó lè ní oúnjẹ ní ìpamọ́ fún àwọn ọmọ ogun mi; àwa yíò sì bá ọ jagun èyítí yíò jẹ́ títí láé, yálà sí mímú àwọn ará Nífáì sí abẹ́ ìjọba wa tàbí sí rírun nwọ́n títí láé. Àti nípa ti Ọlọ́run nnì ẹnití ìwọ wípé àwa ti kọ̀, kíyèsĩ, àwa kò mọ́ irú ẹ̀dá bẹ̃; bákannã ni ẹ̀yin kò mọ̀; ṣùgbọ́n bí ó bá rí bẹ̃ pé irú ẹ̀dá bẹ̃ wà, àwa lérò wípé ó ṣeéṣe pé òun ni ó dá àwa àti ẹ̀yin. Bí ó bá sì jẹ́ wípé èṣù àti ọ̀run àpãdì nbẹ, kíyèsĩ njẹ́ kò ha rán ọ lọ síbẹ̀ láti gbé pẹ̀lú arákùnrin mi tí ìwọ ti pa, ẹnití ìwọ ti sọ wípé ó ti lọ sí ibẹ̀? Ṣùgbọ́n kíyèsĩ àwọn ohun wọ̀nyí kò jámọ́ nkan. Èmi ni Ámmórọ́nì, mo sì jẹ́ ìran Sórámù, ẹnití àwọn bàbá nyín fi ipá mú láti jáde kúrò nínú Jerúsálẹ́mù. Ẹ sì kíyèsĩ nísisìyí, ará Lámánì tí ó gbóyà ni mí; ẹ kíyèsĩ, ogun yĩ ni a jà láti gbẹ̀san nwọn, àti láti gba ẹ̀tọ́ nwọnsí ìjọba; èmi sì parí ìwé mi sí Mórónì. 55 Mórónì kọ̀ láti ṣe pàṣípàrọ̀ àwọn tí a kó lẹ́rú—Nwọ́n tan àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn ará Lámánì láti mu ọtí yó, àwọn ará Nífáì tí a kó lẹ́rú sì di òmìnira—A mú ìlú-nlá Gídì láìsí ìtàjẹ̀sílẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 63 sí 62 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti gba ìwé yìi o binu sĩ ju tatẹhínwa, nítorípé ó mọ̀ wípé Ámmórọ́nì ní ìmọ̀ pípé lórí ìwà àrekérekè ara rẹ̀; bẹ̃ni, ó mọ̀ wípé Ámmórọ́nì mọ̀ pé kìi ṣe nípa èyítí ó tọ́ ni, kí ó bá àwọn ènìyàn Nífáì jagun. Ó sì wípé: Kíyèsĩ, èmi kì yíò ṣe pàṣípàrọ̀ àwọn tí a kó lẹ́rú pẹ̀lú Ámmórọ́nì àfi tí ó bá dawọ ète rẹ̀ dúró, gẹ́gẹ́bí èmi ti wí nínú ọ̀rọ̀ mi; nítorítí èmi kò ní gbà fún un láti ní agbára ju èyítí ó ti ní. Kíyèsĩ, èmi mọ́ ibití àwọn ará Lámánì ti nṣọ́ àwọn ènìyàn mi tí nwọ́n ti kó lẹ́rú; nítorípé Ámmórọ́nì kò sì fifúnmi gẹ́gẹ́bí èmi ti bẽrè nínú ọ̀rọ̀ mi, kíyèsĩ, èmi yíò fifún un gẹ́gẹ́bí èmi ti sọ; bẹ̃ni, èmi yíò lépa ikú lãrín wọn, títí nwọn ó fi bẹ̀bẹ̀ fún àlãfíà. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yĩ, ó mú kí nwọn ṣe ìwákiri lãrín àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, pé bóyá òun yíò rí ẹnìkan tĩ ṣe àtẹ̀lé Lámánì lãrín nwọn. Ó sì ṣe tí nwọ́n rí ẹnìkan, tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Lámánì; ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ ọba tí Amalikíà pa. Nísisìyí Mórónì mú kí Lámánì àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tọ àwọn ẹ̀ṣọ́ tí nṣọ́ àwọn ará Nífáì tí a kó lẹ́rú lọ. Ní báyĩ inú ìlú-nlá Gídì ni nwọ́n ti nṣọ́ àwọn ará Nífáì nnì tí a kó lẹ́rú; nítorínã ni Mórónì ṣe yan Lámánì tí ó sì mú kí díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀. Nígbàtí ó sì di àṣálẹ́ Lámánì tọ àwọn ẹ̀ṣọ́ tí nṣọ́ àwọn ará Nífáì nã lọ, ẹ sì kíyèsĩ, nwọ́n ríi tí ó nbọ̀ nwọ́n sì kíi lókẽrè; ṣùgbọ́n ó wí fún nwọn pé: Ẹ máṣe bẹ̀rù; ẹ kíyèsĩ, ará Lámánì ni èmi í ṣe. Ẹ kíyèsĩ, àwa ti sá àsálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Nífáì, nwọ́n sì nsùn; ẹ sì kíyèsĩ àwa ti bù nínú ọtí nwọn a sì gbée wá. Nísisìyí nígbàtí àwọn ará Lámánì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nwọ́n gbã pẹ̀lú ayọ̀; nwọ́n sì wí fún un pe: Ẹ fún wa nínú ọtí nyín, kí àwa ó mu; inú wa dùn pé ẹ̀yin gbé ọtí wá lọ́nà yĩ nítorítí àwa nṣe ãrẹ̀. Ṣùgbọ́n Lámánì wí fún nwọn pé: Ẹ jẹ́ kí a fi pamọ́ nínú ọtí wa títí àwa yíò fi kọlũ àwọn ará Nífáì ní ogun. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ yĩ túbọ̀ mú nwọn ní ìfẹ́ síi láti mu nínú ọtí nã. Nítorítí nwọ́n wípé: Àwa nkãrẹ̀, nítorínã ẹ jẹ́ kí a mu nínú ọtí nã, àti pé láìpẹ́ àwa yíò gba ọtí tiwa, èyítí yíò fún wa lágbára láti lọ íkọlu àwọn ará Nífáì. Lámánì sì wí fún nwọn pé: Ẹ̀yin lè ṣe gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú nyín. Ó sì ṣe tí nwọ́n mu nínú ọtí nã lọ́pọ̀lọpọ̀; ó sì dùn mọ́ nwọn lẹ́nu, nítorínã ni nwọ́n ṣe musíi; ọtí lílé sì ni í ṣe, nítorií nwọ́n ṣeé kí ó le. Ó sì ṣe tí nwọ́n mu tí nwọ́n sì nyọ̀, tí gbogbo nwọn sì mutí yó láìpẹ́. Àti nísisìyí nígbàtí Lámánì àti àwọn ará rẹ̀ ríi pé gbogbo nwọn ti mutí yó, tí nwọn sì ti sùn lọ, nwọ́n padà sọ́dọ̀ Mórónì nwọ́n sì sọ gbogbo àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ fun. Àti nísisìyí èyí sì wà ní ìbámu pẹ̀lú èrò Mórónì. Mórónì sì ti ṣe ìmúrasílẹ̀ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ohun ìjà-ogun; ó sì lọ sí ìlú-nlá Gídì, nígbàtí àwọn ará Lámánì wà nínú orun tí nwọ́n sì ti mutí yó, nwọ́n sì ju àwọn ohun ìjà-ogun sí àwọn ènìyàn tí a kó lẹ́rú, tóbẹ̃ tí gbogbo nwọn fi di ìhámọ́ra ogun; Bẹ̃ni, àní sí àwọn obìnrin nwọn, àti gbogbo àwọn ọmọ nwọn, gbogbo àwọn tí nwọ́n bá lè lo ohun ìjà-ogun, nígbàtí Mórónì ti di ìhámọ́ra ogun fún àwọn tí a kó lẹ́rú nã; gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí ni nwọ́n sì ṣe ní ìdákẹ́rọ́rọ́. Ṣùgbọ́n bí nwọn bá tilẹ̀ ta àwọn ará Lámánì nã jí, kíyèsĩ nwọ́n ti mutí yó àwọn ará Nífáì ìbá sì pa nwọ́n. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èyí kì í ṣe ìfẹ́ inú Mórónì; kò dunnú sí ìpànìyàn tàbí ìtàjẹ̀sílẹ̀, ṣùgbọ́n ó dunnú sí gbígba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò nínú ìparun; nítorí kí ó má bã bọ́ sínú ipò àìṣòdodo, oun kò ní kọlũ àwọn ará Lámánì kí ó sì pa nwọ́n run nínú ipò ìmutípara tí nwọ́n wà. Ṣùgbọ́n ó ti rí ìfẹ́ inú rẹ̀ gbà; nítorítí ó ti fi ìhámọ́ra ogun di àwọn ará Nífáì tí nwọ́n kó lẹ́rú tí nwọ́n wà nínú odi ìlú-nlá nã, ó sì ti fún nwọn lágbára láti mú àwọn apá ìlú-nlá nã tí ó wà nínú odi ìlú nã. Nígbànã ni ó sì mú kí àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kí nwọ́n padà sẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ nwọn, kí nwọ́n sì ká àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì mọ́. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ nwọ́n ṣe eleyĩ ní òru, tí ó sì jẹ́ wípé nígbàtí àwọn ará Lámánì jí ní òwúrọ̀ nwọ́n ríi pé àwọn ará Nífáì ti ká nwọn mọ́ ní ìta, àti pé àwọn ẹrú nwọn ti di ìhámọ́ra ogun nínú odi ìlú-nlá nã. Báyĩ ni nwọ́n sì ríi pé àwọn ará Nífáì ní agbára lórí nwọn; àti nínú ipò yìi nwọ́n ríi pé kò yẹ kí àwọn ó bá àwọn ará Nífáì jà; nítorínã ni àwọn olórí ológun nwọn ṣe pàṣẹ kí nwọn kó ohun ìjà ogun nwọn lélẹ̀, nwọ́n sì kó nwọn wá síwájú, nwọn si jù nwọn sí ibi ẹsẹ àwọn ará Nífáì, tí nwọ́n sì bẹ̀bẹ̀ fún ãnú. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èyí ni ìfẹ́ inú Mórónì. Ó kó nwọn lẹ́rú, ó sì mú ìlú-nlá nã, ó sì mú kí a tú àwọn tí a ti kó lẹ́rú sílẹ̀ tí nwọ́n jẹ́ ará Nífáì; nwọ́n sì dàpọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì, nwọ́n sì jẹ́ agbára púpọ̀ fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó mú kí àwọn ará Lámánì tí ó kó lẹ́rú bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe láti fi agbára kún àwọn odi tí nwọ́n ti mọ́ kãkiri ìlú-nlá Gídì. Ó sì ṣe nígbàtí ó ti mọ́ odi yí ìlú-nlá Gídì tán, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú rẹ ó mú kí nwọ́n kó àwọn tí a kó lẹ́rú nã lọ sí ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀; ó sì fi àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó lágbára púpọ̀ ṣọ́ ibẹ̀. Ó sì ṣe tí nwọ́n ṣe ìpamọ́ atí ìdãbò bò gbogbo àwọn tí a kó lẹ́rú tí nwọ́n ti mú, l’áìṣírò àwọn ará Lámánì ngbìmọ̀, nwọ́n sì tún di gbogbo àwọn ilẹ̀ ati awọn ánfãní nwọn mú èyítí nwọ́n ti gbà padà. Ó sì ṣe tí àwọn ará Nífáì tún bẹ̀rẹ̀sí nṣẹ́gun, àti láti gba ẹ̀tọ́ àti ìní nwọn padà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn ará Lámánì sì gbìdánwò láti ká nwọ́n mọ́ ní òru, ṣùgbọ́n nínú àwọn àbá wọ̀nyí ni nwọ́n ti pàdánù púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ti nwọn kólẹ́rú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni nwọ́n sì gbìdánwò láti fifún àwọn ará Nífáì mu nínú ọtí nwọn, láti lè pa nwọ́n run pẹ̀lú májèlé tàbí pẹ̀lú ìmutípara. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì ṣe kánkán láti rántí Olúwa Ọlọ́run nwọn ni àkokò ìpọ́njú nwọn yĩ. Nwọn kò rí nwọn mú nínú ìkẹ́kùn nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n kọ̀ láti mu nínú ọtí nwọn, àfi bí nwọ́n bá ti kọ́kọ́ fún nínú àwọn ará Lámánì tí a kó lẹ́rú mu nínú rẹ̀. Báyĩ ni nwọ́n sì ṣe ìjáfáfá pé kí ẹnikẹ́ni máṣe fún nwọn ní májèlé mu lãrín nwọn; nítorípé bí ọtí nwọn bá fi májèlé pa ará Lámánì kan yíò pa ará Nífáì kan pẹ̀lú; báyĩ si ni nwọ́n ndán gbogbo ọtí nwọn wò. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí ó tọ́ fún Mórónì láti ṣe ìmúrasílẹ̀ láti kọlũ ìlú-nlá Móríátọ́nì; nítorí kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì, nípa ipá nwọn, ti dãbò bò ìlú-nlá Mọ́ríátọ́nì títí ó fi di ibi ìsádi tí o lágbára púpọ̀. Nwọ́n sì tẹ̀síwájú nípa kíkó àwọn ọmọ ogun lákọ̀tun wá sínú ìlú-nlá nnì, àti àwọn ìpèsè oúnjẹ lákọ̀tun. Báyĩ sì ni ọdún kọkàndínlọ́gbọ̀n parí nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì. 56 Hẹ́lámánì kọ ìwé ránṣẹ́ sí Mórónì, nínú èyítí ó ti sọ nípa bí ogun nã pẹ̀lú àwọn ará Lámánì ti nlọ—Ántípọ́sì pẹ̀lú Hẹ́lámánì ní ìṣẹ́gun nlá lórí àwọn ará Lámánì—Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹgbẹ̀rún méjì Hẹ́lámánì jà pẹ̀lú agbára ìyanu, kò sì sí èyítí nwọ́n pa nínú nwọn. Ẹsẹ 1, ní ìwọ̀n ọdún 62 kí a tó bí Olúwa wa; ẹsẹ 2 sí 19, ní ìwọ̀n ọdún 66 kí a tó bí Olúwa wa; àti ẹsẹ 20 sí 57, ní ìwọ̀n ọdún 65 sí 64 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ̀n ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, ní ọjọ́ kejì nínú oṣù kíni, Mórónì gba ìwé láti ọ̀dọ̀ Hẹ́lámánì, tí ó sọ nípa ìṣesí àwọn ènìyàn tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ nã. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kọ, wípé: Arákùnrin mi ọ̀wọ́n, Mórónì, nínú Olúwa àti nínú ìpọ́njú ti ogun tí à njà; kíyèsĩ, arákùnrin mi ọ̀wọ́n, mo ní ohun kan láti wí fún ọ nípa ogun tí à njà ní agbègbè yĩ. Kíyèsĩ, ẹgbẹ̀rún méjì nínú àwọn ọmọ àwọn ènìyàn tí Ámọ́nì kó jáde kúrò nínú ilẹ̀ Nífáì—nísisìyí ìwọ ti mọ̀ pé àwọn wọ̀nyí jẹ́ àtẹ̀lé Lámánì, tĩ ṣe ọmọkùnrin tí ó dàgbà jùlọ nínú àwọn ọmọ bàbá wa Léhì; Nísisìyí kò yẹ kí èmi ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún ọ nípa àwọn àṣà tàbíàìgbàgbọ́ nwọn, nítorítí ìwọ mọ̀ nípa gbogbo ohun wọ̀nyí— Nítorínã ni ó ṣe tọ́ fún mi láti wí fún ọ pé ẹgbẹ̀rún méjì nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọ̀nyí ni ó ti kó àwọn ohun ìjà-ogun nwọn, tí nwọ́n sì fẹ́ kí èmi ó jẹ́ olórí nwọn; àwa sì ti jáde wá láti dãbò bò orílẹ̀-èdè wa. Àti nísisìyí ìwọ sì mọ̀ nípa májẹ̀mú tí àwọn bàbá nwọn ti dá, pé àwọn kò ní gbé ohun ìjà nwọn sókè kọlũ àwọn arákùnrin nwọn fún ìtàjẹ̀sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n, nígbàtí nwọ́n rí àwọn ìjìyà wa àti àwọn ìpọ́njú wa lórí nwọn, nwọ́n ṣetán láti sẹ́ májẹ̀mú nã èyítí nwọ́n ti dá kí nwọn sì gbé ohun ìjà-ogun nwọn fún ìdãbò bọ́ wa. Ṣùgbọ́n èmi kò gbà fún nwọn pé kí nwọn sẹ́ májẹ̀mú yĩ èyítí nwọ́n ti dá, nítorípé èmi rọ́ pé Ọlọ́run yíò fún wa ni okun, tóbẹ̃ tí àwa kò ní jìyà mọ́ nítorí ti pípa májẹ̀mú nã mọ́ èyítí nwọ́n ti dá. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ohun kan nìyí nínú èyítí àwa lè ní ayọ̀ púpọ̀. Nítorí kíyèsĩ, nínú ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n nã, èmi; Hẹ́lámánì, lọ níwájú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹgbẹ̀rún méjì yĩ sí ìlú-nlá Jùdéà, láti ran Ántípọ́sì lọ́wọ́, ẹnití ìwọ ti yàn ní olórí lé àwọn ènìyàn tí ó wà ní apá ilẹ̀ nã lórí. Èmi sì dá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi ẹgbẹ̀rún méjì pọ̀, (nítorí nwọ́n yẹ lati pè ní ọmọ) mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ántípọ́sì, nínú agbára èyítí Ántípọ́sì dunnú gidigidi; nítorí kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì ti dín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kù nítorípé àwọn ọmọ ogun nwọn ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọmọ ogun wa, nítorí ìdí èyítí àwa ṣọ̀fọ̀. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwa lè tu ara wa nínú ní ti òtítọ́ yĩ, pé nwọ́n kú nínú ìjà-òmìnira ti orílẹ̀-èdè nwọn àti ní ti Ọlọ́run nwọn, bẹ̃ni, inu nwọn dun. Àwọn ará Lámánì sì ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́rú, gbogbo nwọ́n sì jẹ́ àwọn olórí ológun, nítorítí kò sí ẹlòmíràn tí ó wà lãyè. Àwa sì rọ́ wípé ní àkoko yĩ nwọ́n wà nínú ilẹ̀ Nífáì; báyĩ ni ó sì rí bí nwọ́n kò bá pa nwọ́n. Àti nísisìyí àwọn wọ̀nyí ni àwọn ìlú-nlá ti àwọn ará Lámánì ti gbà fún ìní nípa títa ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ nínú àwọn ọmọ ogun wa akíkanjú sílẹ̀: Ilẹ̀ Mántì, tàbí ìlú-nlá Mántì, àti ìlú-nlá Sísrọ́mù, àti ìlú-nlá Kúménì, àti ìlú-nlá Ántípárà. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ìlúnlá tí nwọ́n gbà fún ìní nígbàtí mo dé inú ìlú-nlá Jùdéà; tí mo sì rí Ántípọ́sì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí nwọn nṣiṣẹ́ tagbáratagbára láti dãbò bò ìlú-nlá nã. Bẹ̃ni, nwọ́n sì kãárẹ̀ ní ara àti ní ẹ̀mí, nítorítí nwọ́n ti jà tagbáratagbára ní ọ̀sán tí nwọ́n sì ṣiṣẹ́ ní alẹ́ láti pa àwọn ìlú-nlá nwọn mọ́; báyĩ sì ni ìyà nlá-nlà lóríṣiríṣi ṣe jẹ nwọ́n. Àti nísisìyí nwọ́n ti pinnu láti ní ìṣẹ́gun ní ibí yĩ tàbí kí nwọ́n kú; nítorínã ìwọ lè rọ́ pé àwọn ọmọ ogun díẹ̀ tí èmi mú wá pẹ̀lú mi yĩ, bẹ̃ni, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi wọnnì, fún nwọn ní ìrètí nlá àti ọ̀pọ̀ ayọ̀. Àti nísisìyí ó sì ṣe pé nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé Ántípọ́sì ti gba agbára kún ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, nípa àṣẹ Ámmórọ́nì ninwọn kò ṣe kọlu ìlú-nlá Jùdéà, tàbí kọlũ wá, ní ogun. Báyĩ sì ni àwa ṣe rí ojú rere Olúwa; nítorípé tí nwọ́n bá kọlu wá ní ipò àìlera yĩ nwọn ìbá ti pa ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa kékèké run; ṣùgbọ́n báyĩ ni Olúwa ṣe pa wá mọ́. Ámmórọ́nì pàṣẹ fún nwọn láti pa àwọn ìlú-nlá tí nwọ́n ti mú mọ́. Báyĩ sì ni ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n parí. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n ni àwa sì palẹ̀ ìlú-nlá wa àti ara wa mọ́ fún ìdãbò bò. Nísisìyí àwa ní ìfẹ́ kí àwọn ará Lámánì wá kọlũ wá; nítorítí àwa kò ní ìfẹ́ láti kọlũ nwọ́n nínú ibi ìsádi nwọn. Ó sì ṣe tí àwa fi àwọn alamí sí àwọn àyíká wa, láti ṣọ́ ìrìn àwọn ará Lámánì, láti má lè kọjá wá ní alẹ́ tàbí ní ọ̀sán láti kọlu àwọn ìlú-nlá wa yókù tí nwọ́n wà ní apá àríwá. Nítorítí àwa mọ̀ pé ní àwọn ìlú-nlá nnì nwọn kò lágbára tó láti dojúkọ nwọn; nítorínã ni àwa ṣe ní ìfẹ́, pé bí nwọ́n bá kọjá lára wa, láti kọlũ nwọ́n láti ẹ̀hìn, kí a sì bá nwọn jà ní apá ẹ̀hìn ní àkokò kannã tí nwọ́n bá nbá nwọn jà ní iwájú. Àwa rò wípé àwa leè borí nwọn; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwa rí ìjákulẹ̀ lórí èrò wa yĩ. Nwọn kò kọjá lára wa pẹ̀lú gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, bẹ̃ni nwọn kò kọjá pẹ̀lú díẹ̀ nínú nwọn, kí nwọ́n má bã wà láìlágbára tó kí nwọ́n ó sì ṣubú. Bẹ̃ni nwọn kò sì kọjá lọ kọlu ìlú-nlá Sarahẹ́múlà; bẹ̃ni nwọn kò sì da orísun odò Sídónì kọjá lọ sínú ìlú-nlá Nífáìhà. Àti báyĩ, pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, nwọ́n pinnu láti di àwọn ìlú-nlá tí nwọ́n ti gbà mú. Àti nísisìyí ó sì ṣe ní oṣù kejì ọdún yĩ, tí àwọn bàbá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi ẹgbẹ̀rún méjì nnì kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèsè oúnjẹ tọ̀ wá wá. Àti pẹ̀lú a fi ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún méjì ránṣẹ́ sí wa láti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Báyĩ sì ni àwa ṣe múrasílẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún mẹ́wã, àti ìpèsè oúnjẹ fún wọn, àti fún àwọn ìyàwó wọn pẹ̀lú àti àwọn ọmọ wọn. Àti àwọn ará Lámánì, nítorípé nwọ́n ríi tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa npọ̀síi lójojúmọ́, tí àwọn ìpèsè oúnjẹ sì nwọlé fún ìtọ́jú wa, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀rù, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sá jáde láti kọlũ wá, láti fi òpin síi fún wa bí ó bá lè rí bẹ̃ fun gbígba àwọn ìpèsè oúnjẹ àti agbára. Nísisìyí nígbàtí a ríi pé àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí wà láìfọkànbalẹ̀ báyĩ, àwa ní ìfẹ́ láti ta ọgbọ́n kan fún wọn; nítorínã Ántípọ́sì pàṣẹ pé kí èmi ó kọjá lọ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi sínú ìlú-nlá kan tí ó wà nítosí, bí ẹnipé à nkó ìpèsè oúnjẹ lọ sínú ìlú-nlá kan tí ó wà nítosí. Àwa sì níláti kọjá lọ nítòsí ìlú-nlá Ántípárà, bí ẹnipé à nlọ sí ìlú-nlá tí ó wà lókè réré, ní ibi ìhà ilẹ̀ létí bèbè òkun. Ó sì ṣe tí àwa kọjá lọ, bí ẹnití nlọ pẹ̀lú ìpèsè oúnjẹ wa, láti lọ sínú ìlú-nlá nã. Ó sì ṣe tí Ántípọ́sì kọjá lọ pẹ̀lú apá kan nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, tí ó sì fi àwọn tí ó kù sílẹ̀ láti dãbò bò ìlú-nlá nã.Ṣùgbọ́n kò kọjá lọ àfi ìgbàtí èmi ti kọjá lọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi kékeré, tí mo sì ti súnmọ́ ìlú-nlá Ántípárà. Àti nísisìyí, ní ìlú-nlá Ántípárà ni nwọ́n fi ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì tí ó lágbára jùlọ sí; bẹ̃ni, èyítí ó pọ̀ púpọ̀ jùlo. Ó sì ṣe, nígbàtí àwọn amí nwọn ti ṣe amí fún nwọn, nwọ́n jáde wá pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn nwọ́n sì kọlũ wá. Ó sì ṣe tí àwa sì sá níwájú nwọn, lọ sí apá àríwá. Báyĩ sì ni àwa tan ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì tí ó lágbára jùlọ, lọ. Bẹ̃ni, àní lọ sí ibití ó jìnà díẹ̀, tóbẹ̃ tí ó fi jẹ́ wípé nígbàtí nwọ́n rí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ántípọ́sì tí ó nsá tẹ̀lé wọn, pẹ̀lú agbára nwọn, nwọn kò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì, ṣùgbọ́n nwọ́n tẹ̀síwájú nínú sísá tẹ̀lé wa; àti pé gẹ́gẹ́bí àwa ṣe rò, èrò ọkàn wọn ni láti pa wá kí Ántípọ́sì tó bá wọn, èyí sì jẹ́ bẹ̃ kí àwọn ènìyàn wa má bã ká wọn mọ́. Àti nísisìyí Ántípọ́sì, nígbàtí ó rí inú ewu tí a wà, ó mú kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ ó kọjá ní kánkán. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ilẹ̀ ti ṣú; nítorínã nwọn kò bá wa, bẹ̃ sì ni Ántípọ́sì kò bá wọn; nítorínã ni àwa ṣe pàgọ́ fún alẹ́ ọjọ́ nã. Ó sì ṣe pé kí ilẹ̀ tó mọ́ ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì nlé wa bọ̀. Nísisìyí, àwa kò lágbára tóbẹ̃ láti bá nwọ́n jà; bẹ̃ni, èmi kò ní jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi ó ṣubú sí nwọn lọ́wọ́; nítorínã ni àwa ṣe tẹ̀síwájú nínú ìrìn wa, tí a sì kọjá lọ sínú aginjù. Nísisìyí nwọn kò yà sí apá ọ̀tun tàbí apá òsì kí nwọn ó má bà lè ká nwọn mọ́; bẹ̃ sì ni emí kò ní yà sí apá ọ̀tún tàbí sí apá òsì kí nwọn ó má bà lè bá mi, àwa kò sì lè dojúkọ nwọ́n, bíkòṣepé nwọn ó pa wá, tí nwọn ó sì sálọ; bayĩ àwa si salọ sínú aginjù ní gbogbo ọjọ́ nã, àní títí ilẹ̀ fi ṣú. Ó sì ṣe pé, nígbàtí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́ a rí àwọn ará Lámánì nã tí nwọ́n nbọ̀ wá bá wa, àwa sì sálọ níwájú nwọn. Ṣùgbọ́n ó ṣe tí nwọn kò lé wa jìnà kí nwọn ó tó dúró; ó sì jẹ́ òwúrọ̀ ọjọ́ kẹ́ta nínú oṣù kéje. Àti nísisìyí, bóyá Ántípọ́sì lé nwọn bá àwa kò mọ̀, ṣùgbọ́n èmi wí fún àwọn ọmọ ogun mi pé: Ẹ kíyèsĩ, àwa lérò wípé nwọ́n dúró nítorítí àwa yíò wá íkọlù nwọ́n, kí nwọn lè mú wa nínú ìkẹ́kùn wọn; Nítorínã kíli ẹ̀yin wí, ẹ̀yín ọmọ mi, njẹ́ ẹ̀yin ó tọ̀ nwọ́n lọ ní ogun? Àti nísisìyí èmi wí fún ọ, arákùnrin mi ọ̀wọ́n Mórónì, pé èmi kò rí irú ìgboyà tí ó tóbi tó èyí rí, rárá, kò sí lãrín àwọn ará Nífáì. Nítorípé bí èmi ti npè nwọ́n ní ọmọ mi (nítorípé ọ̀dọ́mọdé ni gbogbo nwọn) gẹ́gẹ́bí nwọ́n ti nwí fún mi pé: Bàbá, kíyèsĩ Ọlọ́run wa wà pẹ̀lú wa, òun kò sì ní jẹ́ kí a ṣubú; jẹ́ kí a jáde lọ nígbànã; àwa kò ní pa àwọn arákùnrin wa bí nwọ́n bá fi wá sílẹ̀; nítorínã jẹ́ kí a lọ, kí nwọn má bà lè borí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ántípọ́sì. Nísisìyí nwọn kò jà rí síbẹ̀síbẹ̀ nwọn kò bẹ̀rù ikú; nwọ́nsì ronú nípa òmìnira àwọn bàbá nwọn ju bí nwọ́n ti ronú nípa ẹ̀mí ara nwọn; bẹ̃ni, àwọn ìyà nwọn tí kọ́ nwọn, pé bí nwọ́n kò bá ṣiyèméjì, Ọlọ́run yíò kó nwọn yọ. Nwọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ àwọn ìyá wọn fún mi, wípé: Àwa kò ṣiyèméjì pé àwọn ìyá wa mọ̀ bẹ̃. Ó sì ṣe tí mo padà pẹ̀lú àwọn ọmọ mi ẹgbẹ̀rún méjì ní ìdojúkọ àwọn ará Lámánì tí nwọ́n lé wa. Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ántípọ́sì ti lé nwọn bá, ìjà líle sì ti bẹ̀rẹ̀. Nítorítí ó ti rẹ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ántípọ́sì, nítorípé nwọ́n rin ọ̀nà tí ó jìn ní ìwọ̀n ọjọ́ kúkúrú, nwọ́n fẹ́rẹ̀ ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Lámánì; bíkòṣepé èmi padà pẹ̀lú àwọn ọmọ mi ẹgbẹ̀rún méjì nwọn ìbá ti ṣe gẹgẹbi ìpinnu nwọn. Nítorítí Ántípọ́sì ti ṣubú nípasẹ̀ idà, àti púpọ̀ nínú àwọn olórí rẹ̀, nítorípé nwọ́n kãrẹ̀, èyítí ó rí bẹ̃ nítorípé nwọ́n kọjá lọ kánkán—nítorínã àwọn ọmọ ogun Ántípọ́sì, nítorípé ìdàmú bá nwọn nítorí ṣíṣubú àwọn olórí nwọn, bẹ̀rẹ̀sí sálọ kúrò níwájú àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì ní ìgbóyà, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí lé nwọn lọ; báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì nlé wọn lọ pẹ̀lú agbára nígbàtí Hẹ́lámánì kọlũ nwọ́n látẹ̀hìnwá pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ẹgbẹ̀rún méjì, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀, tóbẹ̃ tí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì nã dáwọ́dúró tí nwọ́n sì dojúkọ Hẹ́lámánì. Nísisìyí nígbàtí àwọn ènìyàn Ántípọ̀sì ríi pé ará Lámánì ti yí ẹsẹ̀ padà, nwọ́n kó àwọn ọmọ ogun wọn jọ nwọ́n sì tún padà láti kọlũ àwọn ará Lámánì láti ẹ̀hìn. Àti n í s i s ì y í ó s ì ṣe t í àwa, àwọn ènìyàn Nífáì, àwọn ènìyàn Ántípọ́sì, àti èmi pẹ̀lú àwọn ọmọ mi ẹgbẹ̀rún méjì, ká àwọn ará Lámánì mọ́, tí a sì pa nwọ́n; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi níláti kó àwọn ohun ìjà-ogun nwọn lélẹ̀ àti ara nwọn pẹ̀lú gẹ́gẹ́bí àwọn tí a kó lẹ́rú nínú ogun. Àti nísisìyí ó sì ṣe pé nígbàtí nwọ́n ti jọ̀wọ́ ara nwọn lé wa lọ́wọ́, kíyèsĩ, mo ka àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin nnì tí nwọ́n ti jà pẹ̀lú mi, nítorítí ẹ̀rù bà mí bóyá nwọn ti pa púpọ̀ nínú nwọn. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, sí ayọ̀ nlá mi, kò sí ẹyọkan nínú nwọn tí ó ṣubú lulẹ̀; bẹ̃ni, nwọ́n sì ti jà bí ẹnití ó nlo agbára Ọlọ́run; bẹ̃ni, a kò mọ́ ẹnití ó ti jà pẹ̀lú agbára ìyanu báyĩ rí; àti pẹ̀lú irú ipa títóbi báyĩ tí nwọ́n fi kọlũ àwọn ará Lámánì, tí nwọ́n sì dẹ́rùbà nwọ́n; àti nítorínã ni àwọn ará Lámánì fi jọ̀wọ́ ara nwọn sílẹ̀ bí ẹnití a kó lẹ́rú ní ogun. Àti bí àwa kò ṣe ní ãyè fún àwọn tí a kó lẹ́rú, láti lè máa ṣọ́ nwọn kí a sì mú nwọn kúrò ní ìkáwọ́ ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àwọn ará Lámánì, nítorínã ni àwa ṣe kó nwọn lọ s í i l ẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun Ántípọ̀sì tí nwọn kò pa, pẹ̀lú nwọn; àwọn tí ó kù ni mo mú tí mo sì dàpọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi ará Ámọ́nì nnì, a sì kọjá lọ padà sí ìlú-nlá Jùdéà. 57 Hẹ́lámánì sọ nípa bí nwọ́n ṣe mú Ántípárà àti nípa bí Kúménì ṣe jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ àti ìdáabò bò rẹ̀ nígbàtí ó ṣe—Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ̀ tí í ṣe ará Ámmọ́nì jà takuntakun; gbogbo nwọn ni ó fi ara gba ọgbẹ́, ṣùgbọ́n kò sí èyítí a pa—Gídì sọ nípa pípa tí nwọ́n pa àwọn ará Lámánì tí a kó lẹ́rú àti ìsálọ nwọn. Ní ìwọ̀n ọdún 63 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí èmi gba ìwé kan láti ọwọ́ Ámmórọ́nì, ọba, tí ó wípé bí èmi yíò bá jọ̀wọ́ àwọn ẹnití a ti kó lẹ́rú nnì tí àwa ti mú, òun yíò jọ̀wọ́ ìlú-nlá Ántípárà fún wa. Ṣùgbọ́n èmi kọ ìwé sí ọba nã, wípé ó dá wa lójú wípé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa tó láti mú ìlú-nlá Ántípárà nípa agbára wa; àti pé bí àwa bá jọ̀wọ́ àwọn tí a ti kó lẹ́rú ní ìpãrọ̀ fún ìlú-nlá nã àwa yíò rí bí aláìgbọ́n ènìyàn, àti pé àwa yíò jọ̀wọ́ àwọn tí a kó lẹ́rú ní ìpãrọ̀. Ámmórọ́nì sì kọ àbá mi, nítorítí ó kọ̀ láti ṣe pàṣípàrọ̀ àwọn tí a kó lẹ́rú; nítorínã ni àwa sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìmúrasílẹ̀ láti lọ kọlu ìlú-nlá Ántípárà. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn Ántípárà fi ìlú-nlá nã sílẹ̀, nwọ́n sì sálọ sí àwọn ìlú-nlá nwọn míràn, tí nwọ́n ní ní ìní, láti dãbò bò nwọ́n; báyĩ sì ni ìlú-nlá Ántípárà bọ́ sí ọwọ́ wa. Báyĩ si ni ọdún kéjìdínlọ́gbọ̀n parí nínú ìjọba àwọn onídàjọ́. Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kọkàndínlọ́gbọ̀n, ni àwa gba ìpèsè àwọn oúnjẹ àti àfikún fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa, láti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti làti àwọn ilẹ̀ ti o yiká, ní iye ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àwọn ọmọ ogun, yàtọ̀ sí ọgọ́ta àwọn ọmọ àwọn ará Ámọ́nì tí nwọ́n ti wá darapọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi ẹgbẹ̀rún méjì. Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwa lágbára, bẹ̃ni àwa sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèsè oúnjẹ tí nwọ́n ti kó wá fún wa. Ó sì ṣe tí àwa ní ìfẹ́ láti bá ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí nwọ́n fi ṣọ́ ìlú-nlá Kúménì jagun. Àti nísisìyí kíyèsĩ, èmi yíò fi hàn ọ́ pé àwa yíò mú ìfẹ́ inú wa di ṣíṣe láìpẹ́; bẹ̃ni, pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa tí ó lágbára, tàbí pẹ̀lú apá kan nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa tí ó lágbára, ni àwa ká ìlú-nlá Kúménì mọ́ ní òru, ní kété kí nwọ́n tó gba ìpèsè oúnjẹ nwọn. Ó sì ṣe, tí àwa pàgọ́ yí ìlú-nlá nã ká fún òru ọjọ́ púpọ̀; ṣùgbọ́n àwa sùn pẹ̀lú idà wa, a sì nṣọ́nà, kí àwọn ará Lámánì ó máṣe lè wá kọlũ wá lóru kí nwọ́n sì pa wá, èyítí nwọn gbìyànjú rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà; ṣùgbọ́n a ta ẹ̀jẹ̀ nwọn sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí nwọ́n gbìyànjú. Nígbàtí ó yá ìpèsè oúnjẹ wọn dé, nwọ́n sì ṣetán láti wọ inú ìlú-nlá nã ní alẹ́. T’í àwa, èyítí àwa ìbá fi jẹ́ ará Lámánì, àwa sì jẹ́ ará Nífáì; nítorínã, àwa sì mú nwọn àti àwọn ìpèsè oúnjẹ wọn. Àti l’áìṣírò a ti ké àwọn ará Lámánì kúrò lára ìrànlọ́wọ́ nwọ́n ní ọ̀nà yĩ, nwọ́n sì pinnu láti di ìlú-nlá nã mú; nítorínã ó di dandan fún wa láti kó àwọn ìpèsè nnì kí a sì fi nwọ́n ránṣẹ́ síJùdéà, àti láti fi àwọn ẹrú wa ránṣẹ́ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Ó sì ṣe pé láìpẹ́ ọjọ́ ni àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí sọ ìrètí nù lórí gbígba ìrànlọ́wọ́; nítorínã nwọn jọ̀wọ́ ìlú-nlá nã lé wa lọ́wọ́; báyĩ sì ni àwa ṣe àṣeyọrí lórí ète láti gba ìlú-nlá Kúménì. Ṣùgbọ́n ó ṣe tí àwọn ẹrú wa di púpọ̀ gan-an, l’áìṣírò àwa kò pọ̀ tóbẹ̃, ó di dandan fún wa láti lo gbogbo àwọn ọmọ ogun wa láti ṣọ́ nwọn, tàbí láti pa nwọ́n. Nítorí kíyèsĩ, nwọn a máa já ara nwọn gbà lọ́pọ̀lọpọ̀, nwọn a sì máa jà pẹ̀lú òkúta wẹ́wẹ́, àti pẹ̀lú kùmọ̀, tàbí ohunkóhun tí ọwọ́ nwọn bá bà, tóbẹ̃ tí àwa fi pa oye tí ó ju ẹgbẹ̀rún méjì nínú nwọn lẹ́hìn tí nwọ́n ti jọ̀wọ́ ara nwọn sílẹ̀ fún ìkólẹ́rú. Nítorínã ni ó ṣe di dandan fún wa láti fi òpin sí ìgbe ayé nwọn, tàbí kí a máa ṣọ́ nwọn, pẹ̀lú idà lọ́wọ́, t í t í dé i l ẹ̀ Sarahẹ́múlà; àti pẹ̀lú pé àwọn ìpèsè oúnjẹ wa kò tó mọ́ fún àwọn ènìyàn ara wa, l’áìṣírò àwa ti gbà lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì. Àti nísisìyí, nínú àkokò tí ó léwu yĩ, ó di ohun tí ó ṣe pàtàkì fún wa láti ṣe fún àwọn tí a kó lẹ́rú yĩ; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a pinnu láti rán nwọn lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nítorínã ni a ṣe yan díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun wa, tí a sì fún wọn ní àṣẹ lórí àwọn ẹrú wa wọ̀nyí láti lọ sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Ṣùgbọ́n ó sì se ní ọjọ́ kejì nwọ́n sì padà. Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwa kò bí nwọ́n lẽrè nípa àwọn ẹrú nã; nítorítí kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì nã ti nkọlù wá, nwọ́n sì padà kánkán láti yọ wá kúrò nínú ìṣubú sí ọwọ́ nwọn. Nítorí kíyèsĩ, Ámmórọ́nì ti fi ìpèsè oúnjẹ titun ránṣẹ́ sí nwọn fún ìrànlọ́wọ́ àti ogunlọ́gọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Ó sì ṣe tí àwọn ọmọ ogun nnì tí a rán pẹ̀lú àwọn ẹrú sì padà wá kánkán láti dè nwọ́n lọ́nà, ní bí nwọ́n ṣe fẹ́ borí wa. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́ta nnì jà takuntakun; bẹ̃ni, nwọ́n dúró gbọingbọin níwájú àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì fi ikú pa gbogbo àwọn tí ó takò nwọ́n. Àti bí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa tí ó kù ṣe fẹ́rẹ̀ sá padà níwájú àwọn ará Lámánì, kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́ta nnì dúró gbọingbọin láìfàsẹ́hìn. Bẹ̃ni, nwọ́n sì ṣe ìgbọràn, nwọ́n tiraka láti pa gbogbo àṣẹ mọ́ pátápátá; bẹ̃ni, àti pãpã ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nwọn ni a ṣe ṣeé fún nwọn; èmi sì rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí nwọ́n sọ fún mi pé àwọn ìyá nwọn ni ó kọ́ nwọn. Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ọmọ mi wọ̀nyí, àti àwọn ọmọ ogun nnì tí a ti yàn láti darí àwọn ẹrú nnì, ni àwa jẹ ní gbèsè fún ìṣẹ́gun nlá yĩ; nítorítí àwọn ni ó na àwọn ará Lámánì nã; nítorínã ni a ṣe lé nwọn padà sínú ìlú-nlá Mántì. Àwa sì di ìlú-nlá wa Kúménì mú, nwọn kò sì lè pa gbogbo wa run pẹ̀lú idà; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwa ti pàdánù lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí àwọn ará Lámánì ti sá, ní kía ni mo pàṣẹ pé kí nwọ́n kó àwọn ọmọ ogun mi tí nwọ́n ti fi ara gba ọgbẹ́ kúrò lãrín àwọn tí ó ti kú, tí mo sì mú kí nwọ́n di ọgbẹ́ nwọn. Ó sì ṣe tí igba nínú àwọn ọmọ mi ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́ta nnì, dákú nítorípé nwọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ ṣòfò; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nípa dídára Ọlọ́run, àti sí ìyàlẹ́nu nlá fún wa, àti ayọ̀ gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa pẹ̀lú, kò sí ẹyọ ẹ̀mí kan nínú nwọn tí ó ṣègbé; bẹ̃ni, àti pé kò sì sí ẹyọ ẹ̀mí kan lãrín nwọn tí kò fi ara gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgbẹ́. Àti nísisìyí, ìpamọ́ nwọn jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu sí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa, bẹ̃ni, pé kí a dá wọn sí nígbàtí àwọn ẹgbẹ̀rún nínú àwọn arákùnrin wa ti kú. Àti pé láìṣiyèméjì ni àwa kã kún agbára ìyanu Ọlọ́run, nítorí ìgbàgbọ́ nwọn tí ó tayọ nínú èyítí àwọn ìyá nwọn ti kọ́ nwọn láti gbàgbọ́—pé Ọlọ́run tí ó tọ́ kan nbẹ, àti pé ẹnìkẹ́ni tí kò bá ṣiyèméjì, pé nwọn yíò wà ní ìpamọ́ nípa agbára ìyanu rẹ̀. Nísisìyí èyí ni ìgbàgbọ́ àwọn wọ̀nyí tí èmi ti sọ nípa nwọn; nwọ́n jẹ́ ọ̀dọ́, ọkàn nwọn sì dúró ṣinṣin, nwọ́n sì fi ìgbẹ́kẹ̀lé nwọn sí ínú Ọlọ́run títí lọ. Àti nísisìyí ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí àwa ti tọ́jú àwọn ọmọ ogun wa tí nwọ́n fi ara gba ọgbẹ́ tán báyĩ, tí a sì ti sin àwọn ará wa tí ó kú àti àwọn ará Lámánì tí ó kú pẹ̀lú, tí nwọ́n sì pọ̀, kíyèsĩ, àwa bẽrè lọ́wọ́ Gídì nípa àwọn ẹrú tí nwọ́n ti bẹ̀rẹ̀sí bá lọ sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Nísisìyí Gídì jẹ́ olórí ológun fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí a yàn láti ṣọ́ nwọn lọ sínú ilẹ̀ nã. Àti nísisìyí, àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí Gídì sọ fún mi: Kíyèsĩ, àwa bẹ̀rẹ̀sí lọ sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà pẹ̀lú àwọn ẹrú wa. Ó sì ṣe tí àwa bá àwọn amí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa pàdé, tí nwọ́n ti rán lọ láti ṣọ́ àgọ́ àwọn ará Lámánì. Nwọ́n sì kígbe pè wá wípé— Kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì nkọjá lọ sínú ìlú-nlá Kúménì; sì kíyèsĩ, nwọn yíò kọlũ nwọ́n, bẹ̃ni, nwọn yíò sì pa àwọn ènìyàn wa run. Ó sì ṣe tí àwọn ẹrú wa gbọ́ igbe nwọn, tí ó sì fún nwọn ní ìgboyà; nwọn sì dìde sì wa ní àtakò. Ó sì ṣe nítorí àtakò yĩ tí àwa sì mú kí idà wa ó gbé lù nwọ́n. Ó sì ṣe tí nwọ́n sì rọ́ lu idà wa, nínú èyítí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nwọn kú; tí àwọn tí ó kù sì sá jáde tí nwọ́n sálọ mọ́ wa lọ́wọ́. Sì kíyèsĩ, nígbàtí nwọ́n ti sálọ tí àwa kò sì lè lé nwọn bá, àwa mú ìrìnàjò wa ní kánkán lọ sí ìlú-nlá Kúménì; sì kíyèsĩ, àwa sì dé ibẹ̀ lásìkò láti lè ran àwọn arákùnrin wa lọ́wọ́ láti pa ìlú-nlá nã mọ́. Sì kíyèsĩ, a sì tún yọ wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa. Ìbùkún sì ni fún orúkọ Ọlọ́run wa; nítorítí kíyèsĩ, òun ni ẹnití ó kó wa yọ; bẹ̃ni, tí ó ti ṣe ohun nlá yĩ fún wa. Nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí èmi, Hẹ́lámánì, ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Gídì wọ̀nyí, ayọ̀ kún inú mi lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí dídára Ọlọ́run ní pípa wá mọ́, kí gbogbo wa ó máṣe ṣègbé; bẹ̃ni, èmi sì ní ìdánilójú wípé ẹ̀mí àwọn tí nwọ́n pa ti wọ inú ìsinmi Ọlọ́run nwọn lọ. 58 Hẹ́lámánì, Gídì, àti Tíómnérì fi ẹ̀tàn mú ìlú-nlá Mántì—Àwọn ará Lámánì fà sẹ́hìn—Àwọnọ̀dọ́mọkùnrin àwọn ènìyàn Ámọ́nì ni a pamọ́ bí nwọ́n ṣe wà ní ìdúróṣinṣin nínú ìdãbò òmìnira àti ìgbàgbọ́ nwọn. Ní ìwọ̀n ọdún 63 sí 62 kí a tó bí Olúwa wa. Sì kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe pé ohun tí ó kàn fún wa láti ṣe ni láti mú ìlú-nlá Mántì; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, kò sí bí a ṣe le kó nwọn jáde kúrò nínú ìlú-nlá nã nípa ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa kékeré. Nítorí kíyèsĩ, nwọ́n rántí ohun èyítí àwa ti ṣe ṣãju; nítorínã àwa kò lè tàn nwọ́n kúrò ní àwọn ìsádi nwọn. Nwọ́n sì pọ̀ púpọ̀ ju àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa tí àwa kò lè dáa laba láti lọ kọlũ nwọ́n nínú àwọn ibi ìsádi nwọn. Bẹ̃ni, ó sì di dandan fún wa láti lo àwọn ọmọ ogun wa láti ṣọ́ àwọn apá ilẹ̀ nã tí àwa ti mú ní ìní; nítorínã ó di dandan fún wa láti dúró, kí àwa kí ó lè gba agbára síi láti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà àti àwọn ìpèsè oúnjẹ ní àkọ̀tun. Ó sì ṣe tí èmi ṣe báyĩ rán ikọ̀ sí bãlẹ ilẹ̀ wa, láti jẹ́ kí ó mọ́ ipò tí àwọn ènìyàn wa wà. Ó sì ṣe tí àwa sì dúró láti lè gba ìpèsè oúnjẹ àti agbára láti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ànfàní tí a rí nínú eleyĩ kéré; nítorítí àwọn ará Lámánì nã pẹ̀lú ngba agbára púpọ̀ lójojúmọ́, àti ìpèsè oúnjẹ púpọ̀púpọ̀; báyĩ sì ni ó rí fún wa ní àkokò yí. Àwọn ará Lámánì sì njáde wá láti kọlũ wá láti ìgbà dé ìgbà, nwọ́n sì nta ọgbọ́n láti pa wá run; bíótilẹ̀ríbẹ̃ àwa kò lè jáde wá láti dojú ìjà kọ nwọn, nítorí ti ibi ãbò nwọn àti ibi ìsádi nwọn. Ó sì ṣe tí àwa sì wà nínú ipò ìṣòro yĩ fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, àní títí àwa fi fẹ́rẹ̀ kú fun àìní óunjẹ. Ṣùgbọ́n ó ṣe tí àwa rí oúnjẹ gbà, èyítí àwọn ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún méjì gbé fún wa fún ìrànwọ́ wa; èyí sì ni gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí a rí gbà, láti dãbò bò ara wa àti orílẹ̀-èdè wa kúrò lọ́wọ́ ìṣubú sí ọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, bẹ̃ni, láti bá àwọn ọ̀tá nnì tí kò níye jà. Àti nísisìyí ìdí tí a fi rí irú sísú wọ̀nyí, tàbí pé ìdí tí nwọn kò fi fi ohun ìrànlọ́wọ́ ránṣẹ́ sí wa síi, àwa kò mọ̀; nítorínã ni inú wa fi bàjẹ́ tí a sì kún fún ìbẹ̀rù, pé kí ìdájọ́ Ọlọ́run má bã wá sí órí ilẹ̀ wa, sí ìṣubú àti ègbé wa pátápátá. Nítorínã ni àwa ṣe tú ọkán wa jáde sí Ọlọ́run, nínú adura pé kí ó fún wa ní ágbára kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, bẹ̃ni, kí ó sì fún wa ní ágbára láti lè di àwọn ìlú-nlá wa mú, àti àwọn ilẹ̀ wa, àti àwọn ìní wa, fún ìtọ́jú àwọn ènìyàn wa. Bẹ̃ni, ó sì ṣe tí Olúwa Ọlọ́run wa bẹ̀ wá wò pẹ̀lú ìdánilójú pé òun yíò gbà wá; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí ó sì fi àlãfíà fún ọkàn wa, tí ó sì fún wa ní ìgbàgbọ́ nlá, tí ó sì mú wa ní ìrètí nínú rẹ̀ fún ìdásílẹ̀ wa. Àwa sì tún ní ìgboyà lákọ̀tun pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun kékeré tí a ti gbà, a sì ní ìpinnu tí ó múná láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wa, àti láti di àwọn ilẹ̀ wa mú, àti àwọn ìní wa, àti àwọn ìyàwó wa, àti àwọn ọmọ wa, àti ìjà-òmìnira wa nã. Báyĩ ni àwa sì jáde lọ pẹ̀lú gbogbo agbára wa láti kọlũ àwọn ará Lámánì, tí nwọ́n wàní ìlú-nlá Mántì; àwa sì pàgọ́ wa sí ẹ̀bá aginjù nã, èyítí ó wà nítòsí ìlú-nlá nã. Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kejì, nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé àwa wà ní agbègbè ẹ̀bá aginjù èyítí ó wà nítòsí ìlú-nlá nã, ni nwọ́n rán àwọn amí nwọn kãkiri sí wa kí nwọ́n lè mọ̀ bí a ti pọ̀ tó àti bí agbára wa ti tó. Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n ríi pé àwa kò pọ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn ti pọ̀ tó, àti nítorítí nwọ́n bẹ̀rù pé àwa yíò ké wọn kúrò lára ìrànlọ́wọ́ nwọn àfi bí nwọ́n bá jáde wá láti bá wa jagun kí nwọn sì pa wá, àti pẹ̀lú pé nwọ́n rọ́ pé nwọ́n lè pa wá run ní ìrọ̀rùn pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn, nítorínã ni nwọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìmúrasílẹ̀ láti jáde wá láti bá wa jagun. Nígbàtí àwa sì ríi pé nwọ́n nṣe ìmúrasílẹ̀ láti jáde wá láti kọlù wá, kíyèsĩ, mo mú kí Gídì, pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun díẹ̀, kí ó farapamọ́ nínú aginjù, àti pé kí Tíómnérì àti àwọn ọmọ ogun díẹ̀ farapamọ́ pẹ̀lú sínú aginjù. Nísisìyí Gídì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wà ní apá ọ̀tún àti àwọn tí ó kù sì wa ní apá òsì; nígbàtí nwọ́n sì ti fi ara nwọn pamọ́ báyĩ, kíyèsĩ, èmi dúró, pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó kù, ní ibití àwa ti pàgọ́ wá sí ni àkọ́kọ́ di ìgbànã tí àwọn ará Lámánì yíò jáde wá láti jagun. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì jáde wá pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn láti kọlù wá. Nígbàtí nwọ́n sì ti wá tí nwọ́n sì fẹ́ láti kọlù wá pẹ̀lú idà nwọn, èmi mú kí àwọn ọmọ ogun mi, àwọn tí nwọ́n wà lọ́dọ̀ mi, kí nwọ́n sá padà sínú aginjù. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì nã sá tẹ̀lé wa ní kánkán, nítorítí nwọ́n ní ìfẹ́ láti lé wa bá kí nwọn ó sì pa wá; nítorínã ni nwọ́n ṣe tẹ̀lé wa wọ inú aginjù lọ; àwa sì kọjá lãrín Gídì àti Tíómnérì, tóbẹ̃ tí àwọn ará Lámánì kò rí nwọn. Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Lámánì ti kọjá tán, tàbí pé nígbàtí ẹgbẹ́ ọmọ ogun nã ti kọjá tán, Gídì àti Tíómnérì jáde kúrò ni ibi tí nwọ́n sápamọ́ sí, tí nwọ́n sì ká àwọn amí àwọn ará Lámánì mọ́ kí nwọn ó má lè padà sínú ìlú-nlá nã. Ó sì ṣe, nígbàtí nwọ́n ti ká nwọn mọ́, nwọ́n sáré lọ sínú ìlú-nlá nã nwọ́n sì kọ lu àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó kù tí ó nṣọ́ ìlú-nlá nã, tóbẹ̃ tí nwọ́n pa nwọ́n run tí nwọ́n sì mú ìlú-nlá nã ní ìní. Nísisìyí nwọ́n ṣe eleyĩ nítorípé àwọn ará Lámánì jẹ́ kí nwọ́n ó darí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn lọ sínú aginjù, àfi àwọn ẹ̀ṣọ́ díẹ̀. Ó sì ṣe tí Gídì àti Tíómnérì nípa ọ̀nà yĩ ti rí àwọn ibi ìsádi nwọn gbà ní ìní. Ó sì ṣe tí àwa tẹ̀ síwájú, lẹ́hìn tí a ti rìn jìnà wọ inú aginjù lọ sí apá ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Nígbàtí àwọn ará Lámánì sì rí i pé nwọ́n nkọjá lọ sí apá ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ẹ̀rù bà nwọ́n gidigidi, ní ìbẹ̀rù pé bóyá ète wa ni láti pa nwọ́n run; nítorínã ni nwọ́n ṣe tún bẹ̀rẹ̀sí padà sẹ́hìn sínú aginjù, bẹ̃ni, àní padà sí ọ̀nà ibití nwọ́n ti wá. Sì kíyèsĩ, ilẹ̀ ṣú nwọ́n sì pàgọ́ nwọn, nítorítí àwọn olóríológun àwọn ará Lámánì rò péàwọn ará Nífáì ti nṣãrẹ̀ nítorí ìrìnàjò nwọn; tí nwọ́n sì tún rò pé nwọ́n ti lé gbogbo àwọn ọmọ ogun nwọn nítorínã ni nwọn kò ṣe ronú nípa ìlú-nlá Mántì. Nísisìyí ó sì ṣe pé nígbàtí ilẹ̀ ṣú, mo mú kí àwọn ọmọ ogun mi ó má sùn, ṣùgbọ́n pé kí nwọn ó kọjá lọ síwájú ní ọ̀nà míràn sí ilẹ̀ Mántì. Àti nítorí ìrìn wa ní òru yĩ, kíyèsĩ, ní ọjọ́ kejì àwa ti kọjá àwọn ará Lámánì, tóbẹ̃ tí àwa dé inú ìlú-nlá Mántì ṣãju nwọn. Ó sì ṣe, pé nípa ọgbọ́n yĩ ni àwa ṣe mú ìlú-nlá Mántì láé ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì sì dé itòsí ìlú-nlá nã, tí nwọ́n ríi tí àwa ti ṣe ìmúrasílẹ̀ láti dojúkọ nwọ́n, ẹnu yà nwọ́n gidi, ẹ̀rù sì bà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi sálọ sínú aginjù. Bẹ̃ni, ó sì ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì sá kúrò ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ nã. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nwọ́n ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé pẹ̀lú nwọn jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã. Gbogbo àwọn ìlú-nlá tí àwọn Lámánì sì ti gba, ni ó wà lọ́wọ́ wa ní àkokò yĩ; tí àwọn bàbá wa àti àwọn obìnrin wa àti àwọn ọmọ wa sì npadà sí ilẹ̀ nwọn, gbogbo nwọn àfi àwọn tí nwọ́n ti mú lẹ́rú tí àwọn Lámánì sì ti kó lọ. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa kéré láti ṣọ́ àwọn ìlú-nlá tí ó pọ̀ báyĩ àti ohun ìní tí ó pọ̀ báyĩ. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run wa ẹnití ó ti fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí àwa fi gba àwọn ìlú-nlá nã àti àwọn ilẹ̀ nã, tí í ṣe tiwa. Nísisìyí àwa kò mọ́ ìdí rẹ̀ tí ìjọba kò fi fún wa ní ọmọ ogun síi; bẹ̃ sì ni àwọn ọmọ ogun tí nwọ́n wá sí ọ́dọ̀ wa kò mọ́ ìdí rẹ̀ tí àwa kòì rí ọmọ ogun púpọ̀ gbà síi. Kíyèsĩ, awa kò mọ ṣugbọn bóyá kò ṣeéṣe fún ọ ni, tí ìwọ sì ti kó gbogbo àwọn ọmọ ogun sí ilẹ̀ tí ó wà ní agbègbè ọ̀hún; bí ó bá rí bẹ̃, àwa kò ní ìfẹ́ láti kùn. Bí kò bá sì rí bẹ̃, kíyèsĩ, àwa ní ìbẹ̀rù pé ẹ̀yà wà nínú ìjọba nã, tí nwọn kò fi àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sí wa síi fún ìrànlọ́wọ́ wa; nítorítí àwa mọ̀ wípé nwọ́n pọ̀ ju èyítí nwọ́n fi ránṣẹ́. Ṣùgbọ́n, ẹ kíyèsĩ, kò já mọ́ nkankan—àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run yíò gbà wá, l’áìṣírò ailagbara ẹgbẹ́ ọmọ-ogun wa, bẹ̃ni, yíò sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa. Kíyèsĩ, èyí ni ọdún kọkàndínlọ́gbọ̀n, nígbàtí ó fẹ́rẹ̀ dópin, àwa sì ní àwọn ilẹ̀ wa ní ìní; àwọn ará Lámánì sì ti sálọ sí ilẹ̀ Nífáì. Àwọn ọmọdékùnrin àwọn ènìyàn Ámọ́nì nnì, tí èmi ti sọ̀rọ̀ nípa nwọn, sì wà pẹ̀lú mi nínú ìlú-nlá Mántì; Olúwa si ti ràn nwọ́n lọ́wọ́, bẹ̃ni, ó sì ti gbà nwọ́n lọ́wọ́ ikú idà, tóbẹ̃ tí a kò pa ẹyọkan nínú nwọn. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nwọ́n ti fi ara gba ọgbẹ́ púpọ̀púpọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃ nwọ́n dúró ṣinṣin nínú òmìnira nã nínú èyítí Ọlọ́run ti sọ nwọ́n di òmìnira; nwọ́n sì fi Olúwa Ọlọ́run nwọn sí ọ́kàn lojojúmọ́; bẹ̃ni, nwọ́n sì gbìyànjú láti pa àwọn ìlànà rẹ̀, àti àwọn ìdájọ́rẹ̀, àti àwọn òfin rẹ̀ mọ́ nígbàgbogbo; ìgbàgbọ́ wọn sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ sĩ nínú àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tí nbọ̀wá. Àti nísisìyí, arákùnrin mi ọ̀wọ́n, Mórónì, kí Olúwa Ọlọ́run wa, ẹnití ó ti rà wá padà tí ó sì ti sọ wá di òmìnira, kí ó pa ọ́ mọ́ títí níwájú rẹ̀; bẹ̃ni, kí ó sì fi ojú rere fún àwọn ènìyàn yĩ, àní kí ẹ̀yin ó ní àṣeyọrí láti lè gba gbogbo àwọn ohun tí àwọn ará Lámánì ti gbà lọ́wọ́ wa padà, èyítí ó wà fún ìrànlọ́wọ́ wa. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, èmi fi òpin sí ọ̀rọ̀ mi. Èmi ni Hẹ́lámánì, ọmọ Álmà. 59 Mórónì mú kí Pahoránì fi agbára kún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hẹ́lámánì—Àwọn ará Lámánì gba ìlú-nlá Nífáìhà—Mórónì bínú sí ìjọba. Ní ìwọ̀n ọdún 62 kí a tó bí Olúwa wa. Nísisìyí ó sì ṣe ní ọgbọ̀n ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, lẹ́hìn tí Mórónì ti gbà tí ó sì ti ka ìwé Hẹ́lámánì, inú rẹ̀ dùn púpọ̀ nítorí àlãfíà, bẹ̃ni, àṣeyọrí dáradára tí Hẹ́lámánì ti ní, lórí gbígba àwọn ilẹ̀ tí ó ti sọnù padà. Bẹ̃ni, ó sì ròyìn fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀, nínú gbogbo ilẹ̀ tí ó wà yíká ní apá ibi nã tí ó wà, kí nwọn ó lè yọ̀ pẹ̀lú. Ó sì ṣe tí ó kọ̀wé ránṣẹ́ sí Pahoránì lójú ẹsẹ̀, pé kí ó mú kí àwọn ọmọ ogun péjọ láti fi kún agbára Hẹ́lámánì, tàbí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hẹ́lámánì, nínú èyítí yíò lè se àmójutò apá ilẹ̀ nã ní ìrọ̀rùn, èyítí Ọlọ́run ti fún un ní àṣeyọrí ní ọ̀nà ìyanu láti gbà padà. Ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti fi ìwé yĩ ránṣẹ́ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ó tún bẹ̀rẹ̀sí ṣe ètò láti lè gba àwọn ìní àti àwọn ìlú-nlá tí ó kù èyítí àwọn ará Lámánì ti gbà lọ́wọ́ nwọn. Ó sì ṣe pé bí Mórónì ṣe nṣe ìmúrasílẹ̀ láti lọ kọlũ àwọn ará Lámánì ní ogun, kíyèsĩ, àwọn ènìyàn Nífáìhà, tí nwọ́n ti kójọ papọ̀ láti ìlú-nlá Mórónì àti ìlúnlá Léhì àti ìlú-nlá Mọ́ríátọ́nì, ni àwọn ará Lámánì sì kọlù. Bẹ̃ni, àní àwọn tí nwọ́n ti sá jáde kúrò nínú ilẹ̀ Mántì, àti kúrò nínú àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní àyíká, ni nwọ́n wá tí nwọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì ní apá ilẹ̀ yĩ. Bí nwọ́n sì ti pọ̀ púpọ̀ báyĩ, bẹ̃ni, àti nítorípé nwọ́n ngba ìrànlọ́wọ́ ọmọ ogun lójojúmọ́, nípa àṣẹ Ámmórọ́nì nwọ́n jáde láti kọlũ àwọn ènìyàn Nífáìhà, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n ní ìpakúpa. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn sì pọ̀ púpọ̀ tí àwọn tí ó kù nínú àwọn ènìyàn Nífáìhà níláti sálọ níwájú nwọn; tí nwọ́n sì wá pẹ̀lú tí nwọn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì. Àti nísisìyí nítorítí Mórónì ti lérò pé nwọn yíò fi àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sínú ìlú-nlá Nífáìhà, fún ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí yíò ṣọ́ ìlú-nlá nã, àti nítorípé ó mọ̀ pé ó rọrùn láti pa ìlú-nlá nã mọ́ láti má bọ́ sí ọwọ́ àwọn ará Lámánì jù láti gbã padà lọ́wọ́ nwọn, ó lérò wípé nwọn yíò ṣọ́ ìlú-nlá nã ní ìrọ̀rùn. Nítorínã ni ó ṣe dá àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ dúró láti ṣọ́ àwọn ibití nwọ́n ti gbà padà. Àti nísisìyí, nígbàtí Mórónì ríi pé nwọ́n ti sọ ìlú-nlá Nífáìhà nù ó banújẹ́ púpọ̀púpọ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀sí ṣiyèméjì, nítorí ti ìwà búburú àwọn ènìyàn nã, pé bóyá nwọn kò ní ṣubú sí ọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn. Nísisìyí èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn olórí ológun rẹ̀. Nwọ́n ṣiyèméjì ẹnu sì yà nwọ́n pẹ̀lú nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn nã, èyí sì rí bẹ̃ nítorí àṣeyọrí tí àwọn ará Lámánì ní lórí nwọn. Ó sì ṣe tí Mórónì bínú sí ìjọba nã, nítorí àìnãní òmìnira orílẹ̀ èdè nwọn. 60 Mórónì fi ẹjọ́ sun Pahoránì nípa ti àìfiyèsí ìjọba lórí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun—Olúwa jẹ́ kí nwọ́n pa àwọn olódodo—Àwọn ará Nífáì níláti lo gbogbo ipá àti ìní nwọn láti gba ara nwọn lọ́wọ́ ọ̀tá nwọn—Mórónì kìlọ̀ pé òun yíò bá ìjọba nã jà àfi bí nwọ́n bá fi ìrànlọ́wọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun òun. Ní ìwọ̀n ọdún 62 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí ó tún kọ̀wé sí olórí ilẹ̀ nã, ẹnití íṣe Pahoránì, àwọn wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ tí ó kọ, wípé: Kíyèsĩ, mo kọ ìwé mi sí Pahoránì, tí ó wà nínú ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, ẹnití í ṣe adájọ́ àgbà àti olórí lórí ilẹ̀ nã, àti pẹ̀lú sí gbogbo àwọn tí àwọn ènìyàn yí yàn láti darí àti láti ṣe àkóso ọ̀rọ̀ nípa ti ogun yĩ. Nítorí kíyèsĩ, èmi ní ohun kan láti bá nwọn sọ èyítí í ṣe ìbáwí; nítorí kíyèsĩ, ẹ̀yin fúnra nyín mọ̀ wípé a ti yàn yín láti kó ọmọ ogun jọ, kí ẹ sì dì nwọ́n ní ìhámọ́ra pẹ̀lú idà àti pẹ̀lú doje-ija àti onírũrú ohun ìjà-ogun lóríṣiríṣi, kí ẹ sì rán nwọn jáde lọ kọlu àwọn ará Lámánì, níbikíbi tí nwọn lè gbà jáde wá sínú ilẹ̀ wa. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, mo wí fun nyín pé èmi fúnra mi, àti àwọn ọmọ ogun mi pẹ̀lú, àti Hẹ́lámánì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú, ti jìyà lọ́pọ̀lọpọ̀; bẹ̃ni, àní ebi, òùngbẹ, àti ãrẹ̀, àti onírũrú ìpọ́njú lóríṣiríṣi. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, njẹ́ bí ó bá jẹ́ wípé èyí nìkan ni ìyà tí ó jẹ wá àwa kì bá ti kùn tàbí kí a ráhùn. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìpakúpa nã pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ lãrín àwọn ènìyàn wa; bẹ̃ni, ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ti subú nípa ti idà, èyítí kì bá tí rí bẹ̃ bí ẹ̀yin bá ti fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa ní agbára àti irànlọ́wọ́ tí ó tó. Bẹ̃ni, ìpatì nyin sí wa pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwa nífẹ́ láti mọ́ ohun tí ó fa irú ìpatì nlá yĩ; bẹ̃ni, àwa nífẹ́ láti mọ́ ohun tí ó fa irú ìwà àìnírònú nyín yĩ. Njẹ́ ẹ̀yin lérò pé ẹ̀yin lè jókó sí órí ìtẹ́ nyín ní ipò àìnírònú aláìníyè yĩ, kí àwọn ọ̀tá nyín ó sì máa tan iṣẹ́ ìpànìyàn kákiri lãrín nyín? Bẹ̃ni, bí nwọ́n ṣe npa ẹgbẹ̃gbẹ̀rún nínú àwọn arákùnrin nyín— Bẹ̃ni, àní àwọn tí nwọ́n gbẹ́kẹ̀lé nyín fún ãbò, bẹ̃ni, tí nwọ́n fi nyín sí ípò tí ó yẹ fún nyín láti ràn nwọ́n lọ́wọ́, bẹ̃ni, ẹ̀yin ìbá ti fi àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ránṣẹ́ sí nwọn, láti fún nwọn ni ágbára, ẹ̀yin ìbá sì ti gba ẹgbẹ̃gbẹ̀rún nwọn lọ́wọ́ ìṣubú nipasẹ idà. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ èyí kì i ṣe gbogbo rẹ̀—ẹ̀yin fà ọwọ́ ìpèsè oúnjẹ sẹ́hìn fún nwọn, tóbẹ̃ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ jà tí nwọ́n sì ṣẹ̀jẹ̀ kú nítorí ti ìfẹ́ nlá tí nwọ́n ní fún àlãfíà àwọn ènìyàn yĩ; bẹ̃ni, eleyĩ ni nwọ́n sì ṣe nígbàtí nwọ́n fẹ́rẹ̀ kú fún ebi, nítorí ìpatì nlá nyín sí nwọn. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́—nítorípé ó yẹ kí ẹ̀yin ó jẹ́ àyànfẹ́; bẹ̃ni, ó sì yẹ kí ẹ̀yin ti ta ara nyín jí gírí fún àlãfíà àti òmìnira àwọn ènìyàn yĩ; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ẹ̀yin ti pa nwọ́n tì tóbẹ̃ tí ẹ̀jẹ̀ ẹgbẹ̃gbẹ̀rún yíò wá sórí nyín fún ẹ̀san; bẹ̃ni, nítorítí gbogbo igbe nwọn àti gbogbo ìyà nwọn jẹ́ mímọ̀ sí Ọlọ́run— Kíyèsĩ, ẹ̀yin ha lérò wípé ẹ lè joko lórí ìtẹ́ nyín bí, àti pé nítorí dídára Ọlọ́run tí ó pọ̀ púpọ̀ ẹ̀yin kò ní ṣe ohun kankan òun yíò sì gbà nyín? Ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin rọ́, ẹ rọ́ lásán ni. Ẹ̀yin ha lérò wípé, pípa ti á pa púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin nyín nítorí ìwà búburú nwọn ni bí? Èmi wí fún nyín, bí ẹ̀yin bá lérò báyĩ ẹ̀yin rọ́ lórí asán ni; nítorítí mo wí fún nyín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ti ṣubú nípa idà; àti pé kíyèsĩ sí ìdálẹ́bi nyín ni; Nítorítí Olúwa jẹ́ kí a pa olódodo kí àìṣègbè àti ìdájọ́ rẹ̀ lé wá sórí àwọn ènìyàn búburú; nítorínã kí ẹ̀yin ó máṣe ró wípé àwọn olódodo yíò ṣègbé nítorítí a ti pa nwọn; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nwọ́n wọ inú ìsinmi Olúwa Ọlọ́run nwọn. Àti nísisìyí kíyèsĩ, mo wí fún nyín, mo ní ìbẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run yíò wá sí órí àwọn ènìyàn yĩ, nítorí ìwà ìmẹ́lẹ́ nwọn, bẹ̃ni, àní ìwà ìmẹ́lẹ́ ìjọba wa, àti ìpatì nlá nwọn sí àwọn arákùnrin nwọn, bẹ̃ni, sí àwọn tí nwọ́n ti pa. Nítorí bíkòbáṣe ti ìwà búburú èyítí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí wa, àwa ìbá ti dojúkọ àwọn ọ̀tá wa tí nwọn kò sì ní lè borí wa. Bẹ̃ni, bíkòbáṣe nítorí ogun tí ó bẹ́ sílẹ̀ lãrín wa; bẹ̃ni, bí kò bá ṣe nítorí àwọn afọbajẹ wọ̀nyí, tí nwọ́n fa ìtàjẹ̀sílẹ̀ púpọ̀ lãrín wa; bẹ̃ni ní àkokò tí àwa nbá ara wa jà, bí àwa bá ti fọwọ́sowọ́pọ̀ nínú agbára bí àwa ti ṣe tẹ́lẹ̀; bẹ̃ni, bí kò bá ṣe nítorí ti ìfẹ́ fún agbára àti àṣẹ èyítí àwọn afọbajẹ wọ̀nnì ní lórí wa; bí nwọ́n bá ti ṣe òtítọ́ sí ìjà-òmìnira nã, tí nwọ́n sì ti darapọ̀ mọ́ wa, tí nwọ́n sì jáde lọ dojúkọ àwọn ọ̀tá wa, dípò kí nwọ́n gbé idà nwọn sí wa, èyítí ó jẹ́ ohun tí ó fa ìtàjẹ̀sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ lãrín ara wa; bẹ̃ni, bí àwa bá ti jáde lọ láti dojúkọ nwọ́n nínú agbára Olúwa, àwa ìbá ti tú àwọn ọ̀tá wa ká, nítorípé èyí ìbá ti rí bẹ̃, ní ìbámu pẹ̀lú ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, nísisìyí àwọn ará Lámánì ngbógun tì wá, nwọ́n sì ngba àwọn ilẹ̀ wa, nwọ́n sì npa àwọn ènìyàn wa pẹ̀lú idà, bẹ̃ni, àwọn obìnrin wa àti àwọn ọmọ wa, nwọ́n sì nkó nwọn lọ ní ìgbẹ̀kùn, tí nwọ́n sì njẹ́ kí onírũrú ìyà jẹ nwọ́n, èyí sì rí bẹ̃ nítorí ti ìwà búburú àwọn tí nwá agbára àti àṣẹ, bẹ̃ni, àní àwọn afọbajẹ wọnnì. Ṣùgbọ́n èmi yíò ha ṣe sọ̀rọ̀ púpọ̀ lórí ohun yĩ? Nítorítí àwa kò mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe pé ẹ̀yin tìkara yín nwá àṣẹ́. Àwa kò mọ̀,ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe pé ọlọ̀tẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú í ṣe sí ìlú nyín. Tàbí ẹ̀yin ha ti pawá tì nítorípé ẹ̀yin wà ní ãrin inú ilẹ̀ orílẹ̀-èdè wa tí ãbò sì yí nyín ká, ni ẹ̀yin kò ṣe mú kí a fi oúnjẹ ránṣẹ́ sí wa, àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun pẹ̀lú láti lè fi agbára kún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa? Ẹ̀yin ha ti gbàgbé àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run nyín bí? Bẹ̃ni, ẹ̀yin ha ti gbàgbé ìkólọ sí ìgbèkún àwọn bàbá wa bí? Ẹ̀yin ha ti gbàgbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ igbà tí Ọlọ́run ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa bí? Tabí ẹ̀yin ha lérò wípé Olúwa yíò tún gbà wá, bí àwa ti joko lórí ìtẹ́ wa tí àwa kò sì mú ohun tí Olúwa ti pèsè fún wa lò bí? Bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin yíò ha jókó láìṣiṣẹ́ tí ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àwọn wọnnì sì yí nyín ká, bẹ̃ni, àti ẹgbẹ̃gbẹ̀rún mẹwa, àwọn wọnnì tí nwọ́n sì joko láìṣiṣẹ́ pẹ̀lú, nígbàtí àwọn ẹgbẹ̃gbẹ̀rún wà kákiri ní agbègbè ilẹ̀ nã tí nwọ́n ṣubú nípa idà, bẹ̃ni, tí nwọ́n ti fi ara gba ọgbẹ́ tí nwọ́n sì nṣẹ́jẹ̀? Ẹ̀yin ha lérò wípé Ọlọ́run yíò wò nyín pé ẹ̀yin wà láìlẹ́bi nígbàtí ẹ̀yin joko jẹ́jẹ́ tí ẹ sì nwo àwọn ohun wọ̀nyí? Kíyèsĩ mo wí fún nyín, rárá. Nísisìyí èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó rántí pé Ọlọ́run ti wípé a ó kọ́kọ́ wẹ àgọ́ inú ara mọ́, lẹ́hìnnã sì ni a ó wẹ àgọ́ ara òde mọ́ pẹ̀lú. Àti nísisìyí, àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà ní ti èyítí ẹ̀yin ti ṣe, kí ẹ sì dìde sí iṣẹ́, kí ẹ sì fi oúnjẹ àti àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sí wa, àti sí Hẹ́lámánì pẹ̀lú, kí ó lè dãbò bò àwọn apá ilẹ̀ wa nã tí ó ti gbà padà, àti pé kí àwa nã ó lè gba àwọn ohun-ìní wa tí ó kù ní àwọn apá ilẹ̀ yĩ padà, ẹ kíyèsĩ ó yẹ kí àwa ó máṣe bá àwọn ará Lámánì jà mọ́ títí àwa ó fi kọ́kọ́ wẹ àgọ́ inú ara wa mọ́, bẹ̃ni, àní àwọn olórí àgbà ìjọba wa. Àti pé àfi bí ẹ̀yin bá fifún mi gẹ́gẹ́bí èmi ti bẽrè nínú ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ sì fi ẹ̀mí òmìníra ní tọ́tọ́ hàn mi ní gbangba, kí ẹ sì tiraka láti fi agbára kún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa, kí ẹ sì fún nwọn ní oúnjẹ fún àtìlẹhìn nwọn, ẹ kíyèsĩ èmi yíò fi apá kan nínú àwọn ènìyàn olómìnira mi sílẹ̀ láti dãbò bò ilẹ̀ wa tí ó wà ní apá yĩ, èmi yíò sì fi agbára àti ìbùkún Ọlọ́run sílẹ̀ sórí nwọn, kí agbára míràn máṣe lè bá nwọn jà— Èyí sì rí bẹ̃ nítorí ìgbàgbọ́ nwọn tí ó tóbi, àti sũrù nwọn nínú ìpọ́njú— Èmi yíò sì tọ̀ nyín wá, bí ẹnìkẹ́ni bá sì wà lãrín nyín tí ó ní ìfẹ́ fún òmìnira, bẹ̃ni, bí a bá rí ìfẹ́ fún òmìnira bí ó ti wulẹ̀ kí ó kéré tó, kíyèsĩ èmi yíò dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ lãrín nyín, àní títí àwọn tí ó ní ìfẹ́ láti gba agbára àti àṣẹ yíò fi di aláìsí. Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ èmi kò bẹ̀rù agbára nyín tàbí àṣẹ nyín, ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi ni ẹnití èmi bẹ̀rù rẹ̀; gẹ́gẹ́bí ìpaláṣẹ rẹ̀ ni èmi sì fi gbé idà mi láti dãbò bò ipa ọ̀nà ìfẹ́ orílẹ̀-èdè mi, àti nítorí àìṣedẽdé nyín ni àwa ṣe rí àdánù tí ó pọ̀ báyĩ. Ẹ kíyèsĩ àsìkò ti tó, bẹ̃ni, àkokò nã ti dé tán, pé àfi bí ẹ̀yin bá ta ara nyín jí fún ìdãbò bò orílẹ̀-èdè nyín àti àwọn ọmọ nyín, idà yíò wà ní gbígbé sókè lórí nyín; bẹ̃ni, yíò sì kọlũ nyíntí yíò sì bẹ̀ nyín wò àní sí ìparun nyín pátápátá. Kíyèsĩ, èmi ndúró de ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ nyín; àti pé, àfi bí ẹ̀yin bá ràn wá lọ́wọ́, ẹ kíyèsĩ, èmi yíò tọ̀ nyín wá, àní nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, èmi yíò sì kọlũ nyín pẹ̀lú ida, tó bẹ̃ tí ẹ̀yin kò lè ní agbára mọ́ láti dá itẹsiwaju àwọn ènìyàn yĩ duro nínú ija fun ipa ominira wa. Nítorí ẹ kíyèsĩ, Olúwa kò ní jẹ́ kí ẹ̀yin wà lãyè kí ẹ sì di alágbára nínú àìṣedẽdé nyín láti lè pa àwọn ènìyàn rẹ̀ tí í ṣe olódodo run. Kíyèsĩ, ẹ̀yin ha lérò wípé Olúwa yíò dá nyín sí tí yíò sì ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ará Lámánì, nígbàtí ó ṣe wípé àṣà àwọn bàbá nwọn ni ó fa ìkorira tí nwọ́n ní, bẹ̃ni, tí àwọn tí nwọ́n fẹ́ yapa kúrò lára wa sì tún sọọ́ di ìlọ́po síi, nígbàtí ìwà búburú nyín sì wà nítorí ìfẹ́ nyín fún ògo àti ohun asán ayé yĩ bí? Ẹ̀yin mọ̀ wípé ẹ̀yin rékọjá sí òfin Ọlọ́run, ẹ̀yin sì mọ̀ wípé ẹ̀yin ntẹ̃ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ nyín. Kíyèsĩ, Olúwa wí fún mi pé: Bí àwọn tí ẹ̀yin ti yàn gẹ́gẹ́bí aláṣẹ nyín kò bá ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn àìṣedẽdé nwọn, ìwọ yíò lọ kọlũ nwọ́n ní ìjà. Àti nísisìyí kíyèsĩ, èmi, Mórónì, ó di dandan fún mi nípa májẹ̀mú tí èmi ti dá láti pa òfin Ọlọ́run mi mọ́; nítorínã ni èmi ṣe fẹ́ kí ẹ̀yin ó ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ẹ sì ránṣẹ́ sí mi ní kánkán pẹ̀lú àwọn ìpèsè oúnjẹ àti àwọn ọmọ ogun nyín, àti sí Hẹ́lámánì. Sì kíyèsĩ, bí ẹ̀yin kò bá ṣe èyí èmi nbọ̀ wá bá nyín kánkán; nítorí ẹ kíyèsĩ, Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí àwa ó kú lọ́wọ́ ebi; nítorínã yíò fifún wa nínú oúnjẹ nyín, àní bí ó tilẹ̀jẹ́wípé nípa idà. Nísisìyí kí ẹ ríi pé ẹ̀yin mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ. Kíyèsĩ, èmi ni Mórónì, tí í ṣe balógun àgbà nyín. Èmi kò lépa agbára, bíkòṣe láti wóo lulẹ̀. Èmi kò wá ọlá ti inú ayé yĩ, ṣùgbọ́n fún ògo Ọlọ́run mi, àti ominira àti ìwà àlãfíà orílẹ̀-èdè mi. Báyĩ sì ni èmi pará ọ̀rọ̀ mi. 61 Pahoránì sọ fún Mórónì nípa ìṣọ̀tẹ̀ àti ìtàpásí ìjọba nã—Àwọn afọbajẹ nã gba Sarahẹ́múlà nwọ́n sì bá àwọn ará Lámánì ní àjọṣepọ̀—Pahoránì bẽrè fún ìrànlọ́wọ́ ọmọ ogun láti lè kọlũ àwọn ọlọ̀tẹ̀ nã. Ní ìwọ̀n ọdún 62 kí a tó bí Olúwa wa. Kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe, pé ní kété tí Mórónì ti fi ìwé rẹ̀ ránṣẹ́ sí aláṣẹ àgbà nã, ó gba ìwé láti ọ̀dọ̀ Pahoránì aláṣẹ àgbà. Àwọn yĩ sì ni ọ̀rọ̀ tí ó gbà: Èmi, Pahoránì, tí í ṣe aláṣẹ àgbà lórí ilẹ̀ yĩ, fi àwọn ọ̀rọ̀ yĩ ránṣẹ́ sí Mórónì, tí í ṣe olórí ológun lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Kíyèsĩ, mo wí fún ọ́, Mórónì, pé inú mi kò dùn nípa ìpọ́njú nyín tí ó pọ̀ púpọ̀, bẹ̃ni, ó bá ọkàn mi jẹ́. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn kan wà tí inú nwọn ndùn sí ìpọ́njú nyín, bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí nwọ́n ti dìde ní ìṣọ̀tẹ̀ sí mi, àti sí àwọn ènìyàn mi tí nwọn jẹ́ àwọn tí nwá òmìnira, bẹ̃ni, àwọn tí nwọ́n dìde sì pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Àti pé àwọn tí nwọn nlépa láti gba ìtẹ́ ìdájọ́ lọ́wọ́ mi ni nwọ́nnṣe àìṣedẽdé nlá yĩ; nítorítí nwọ́n lo ẹ̀tàn nlá, nwọ́n sì ti darí ọkàn àwọn ènìyàn púpọ̀ sí ṣíṣe búburú, èyítí yíò fa ìpọ́njú tí ó pọ̀ lãrín wa; nwọ́n ti dáwọ́ fífún wa ní ìpèsè oúnjẹ wa dúró nwọ́n sì ti dẹ́rùba àwọn ènìyàn olómìnira wa tóbẹ̃ tí nwọn kò lè wá bá nyín. Sì kíyèsĩ, nwọ́n ti lé mi jáde kúrò níwájú wọn, èmi sì ti sálọ sí ilẹ̀ Gídéónì, pẹ̀lú iye àwọn ọmọ ogun tí ó ṣeéṣe fún mi láti mú tọwọ. Sì kíyèsĩ, èmi ti kọ ìwé ikede ránṣẹ́ jákè-jádò apá ilẹ̀ tí ó wà ní ibi yĩ; sì kíyèsĩ, nwọ́n darapọ̀ mọ́ wa lójojúmọ́, láti gbé ohun ìjà ogun nwọn, ní ìdãbò bò orílẹ̀èdè nwọn àti òmìnira nwọn, àti láti gbẹ̀san ìwà ìkà nwọn. Nwọ́n sì ti wá bá wa, tóbẹ̃ tí nwọn ntako àwọn tí nwọ́n ti dìde ní ìṣọ̀tẹ̀ sí wa, bẹ̃ni, tóbẹ̃ ti nwọn bẹru wa tí nwọn kò lè dá àbá láti jáde wá dojú ìjà kọ wá. Nwọ́n ti gba ilẹ̀ nã, tàbí olú ìlú nã, Sarahẹ́múlà; nwọ́n ti yan ọba lórí nwọn, òun sì ti kọ̀wé sí ọba àwọn ará Lámánì, nínú èyítí ó ti bã ní májẹ̀mú àjọṣepọ̀; nínú àjọṣepọ̀ èyítí ó gbà láti dãbò bò ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, ìdãbò bò èyítí òun lérò wípé yíò mú kí àwọn ará Lámánì lè ṣẹ́gun èyítí ó kù nínú ilẹ̀ nã, tí nwọn ó sì fi jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn yĩ nígbàtí àwọn ará Lámánì yíò ṣẹ́gun nwọn. Àti nísisìyí, nínú ọ̀rọ̀ rẹ ìwọ ti bá mi wí, ṣùgbọ́n kò já mọ́ nkan; èmi kò bínú, ṣùgbọ́n mo láyọ̀ nínú ìdúróṣinṣin rẹ. Èmi, Pahoránì, kò lépa agbára, bíkòṣe láti lè di ìtẹ́ ìdájọ́ mi mú kí èmi ó lè pa ẹ̀tọ́ àti òmìnira àwọn ènìyàn mi mọ́. Ọkàn mi dúró ṣinṣin nínú òmìnira nã nínú èyítí Ọlọ́run ti sọ wá di òmìnira. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, àwa yíò tako ìwà búburú àní títí dé ojú ìtàjẹ̀sílẹ̀. Àwa kò ní ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ará Lámánì silẹ bí nwọn yíò bá dúró nínú ilẹ̀ nwọn. Àwa kò ní ta ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin wa sílẹ̀ bí nwọn kò bá dìde ní ìṣọ̀tẹ̀ kí nwọ́n sì gbé idà kọlũ wá. Àwa yíò fi ara wa fún àjàgà oko-ẹrú tí ó bá wà ní ìbámu pẹ̀lú àìṣègbè Ọlọ́run, tàbí bí ó bá pãláṣẹ fún wa láti ṣe bẹ̃. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ òun kò pãláṣẹ fún wa pé kí àwa ó fi ara wa fún àwọn ọ̀tá wa, ṣùgbọ́n pé kí àwa ó gbẹ́kẹ̀ wa lé e, òun yíò sì gbà wá. Nítorínã, arákùnrin mi àyànfẹ́, Mórónì, ẹ jẹ́ kí àwa ó tako èyítí ó burú, àti pé ohun búburú èyítí ó wù tí àwa kò bá lè takò pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wa, bẹ̃ni, gẹ́gẹ́bí ìṣọ̀tẹ̀sí àti ìyapa, ẹ jẹ́ kí a takò nwọn pẹ̀lú idà wa, kí àwa ó lè di òmìnira wa mú, kí àwa ó lè yọ nínú anfãni nla ti ìjọ-onígbàgbọ́ wa, àti nínú ipa ti ìfẹ́ Olùràpadà wá àti Ọlọ́run wa. Nítorínã, wá sí ọ̀dọ̀ mi ní kánkán pẹ̀lú díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ, kí o sì fi àwọn tí ó kù sí abẹ́ Léhì àti Tíákúmì; fún nwọn ní àṣẹ láti ja ogun ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá ibẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú Ẹ̀mí Ọlọ́run, èyítí í ṣe ẹ̀mí ìtúsílẹ̀ èyítí nbẹ nínú nwọn. Kíyèsĩ èmi ti fi ìpèsè oúnjẹ díẹ̀ ránṣẹ́ sí nwọn, kí nwọn ó má bã ṣègbé títí ẹ̀yin ó fi wá bá mi. Kó àwọn ọmọ ogun èyíkeyĩ tí ìwọ bá rí jọ nígbàtí ẹ̀yin bá nbọ̀wá sí ìhín, àwa yíò sì lọ kánkán láti kọlũ àwọn olùyapa nnì, nínú ipá Ọlọ́run wa ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí ó wà nínú wa. Àwa yíò sì gba ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, kí àwa ó lè rí oúnjẹ síi láti fi ránṣẹ́ sí Léhì àti Tíákúmì; bẹ̃ni, àwa yíò lọ láti kọlũ nwọ́n nínú ipá Olúwa, àwa yíò sì fi òpin sí ìwà àìṣedẽdé nlá yĩ. Àti nísisìyí, Mórónì, inú mi dùn láti gba ìwé rẹ, nítorípé agara dá mi nípa ohun tí ó yẹ kí àwa ó ṣe, bóyá ó tọ́ fún wa láti kọlũ àwọn arákùnrin wa. Ṣùgbọ́n ìwọ ti wípé, àfi bí nwọ́n bá ronúpìwàdà Olúwa ti pãláṣẹ fún ọ pé kí ìwọ ó kọlũ nwọ́n. Kí o ríi pé o ti Léhì àti Tíákúmì lẹ́hìn nínú ìgbàgbọ́ nwọn nínú Olúwa; wí fún nwọn pé kí nwọn máṣe bẹ̀rù, nítorítí Ọlọ́run yíò gbà nwọ́n, bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn tí ó dúró ṣinṣin nínú òmìnira nnì nínú èyítí Ọlọ́run ti sọ nwọ́n di òmìnira. Àti nísisìyí èmi parí ọ̀rọ̀ mi sí arákùnrin mi àyànfẹ́, Mórónì. 62 Mórónì kọjá lọ láti ran Pahoránì lọ́wọ́ ní ilẹ̀ Gídéónì—Nwọ́n pa awọn afọbajẹ tí nwọ́n kọ̀ láti dãbò bò orílẹ̀-èdè nwọn—Pahoránì àti Mórónì gba Nífáìhà padà—Àwọn ará Lámánì púpọ̀ darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ámọ́nì—Tíákúmì pa Ámmórọ́nì nítorí ìdí èyí ni nwọ́n sì pa òun nã—À lé àwọn ará Lámánì kúrò ní ilẹ̀ nã, a sì fi àlãfíà lélẹ̀—Hẹ́lámánì padà sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ó sì gbé iṣẹ́ Ìjọ-Ọlọ́run sókè. Ní ìwọ̀n ọdún 62 sí 57 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti gba ìwé yĩ, ó gba ìmúlọ́kànle, ó sì kún fún ayọ̀ púpọ̀ nítorí ìgbàgbọ́ Pahoránì, pé kĩ ṣe ọlọ̀tẹ̀ sí òmìnira àti ìjà-òmìnira ti orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó sì kẹ́dùn ọkàn lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú nítorí àìṣedẽdé àwọn tí nwọ́n lé Pahoránì kúrò lórí ìtẹ́ ìdájọ́, bẹ̃ni, ní kúkúrú nítorí ti àwọn tí nwọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí orílẹ̀-èdè nwọn àti sí Ọlọ́run nwọn pẹ̀lú. Ó sì ṣe tí Mórónì mú díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Pahoránì, ó sì fún Léhì àti Tíákúmì ní àṣẹ lórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ó kù, ó sì kọjá lọ sí apá ilẹ̀ Gídéónì. Ó sì gbé àsíá òmìnira sókè níbikíbi tí ó bá wọ̀, ó sì kó gbogbo ọmọ ogun tí ó bá ṣeéṣe fún un láti kójọ bí ó ti nkọjá lọ sí apá ilẹ̀ Gídéónì. Ó sì ṣe tí ẹgbẽgbẹ̀rún nwọn sì darapọ̀ mọ̀ ọ́, tí nwọ́n sì gbé idà nwọn láti dãbò bò òmìnira nwọn, pé kí nwọ́n má lè bọ́ sínú oko-ẹrú. Àti báyĩ, nígbàtí Mórónì ti kó gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó rí jọ pọ̀ bí ó ti nkọjá lọ, ó dé ilẹ̀ Gídéónì; nígbàtí ó sì ti da àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́ ti Pahoránì nwọ́n ní ágbára lọ́pọ̀lọpọ̀, àní nwọ́n ní ágbára ju àwọn ọmọ ogun Pákúsì, tĩ ṣe ọba àwọn olùyapa nnì tí nwọ́n lé àwọn ẹnití nwá òmìnira nnì jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà tí nwọ́n sì ti gba ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí Mórónì àti Pahoránì kọjá lọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí nwọ́n sì jáde lọ ní ìkọlù ìlú-nlá nã, nwọ́n sì bá àwọn ọmọ ogun Pákúsì pàdé, tóbẹ̃ tí nwọ́n sì wá bá nwọn jagun. Ẹ kíyèsĩ, a pa Pákúsì a sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lẹ́rú, a sì dá Pahoránì padà sórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Pákúsì sì gba ìdájọ́ nwọn, ní ìbámu pẹ̀lú òfin, àti àwọn afọbajẹ nnì tí a ti mú tí a sì tĩ jù sínú túbú; a sì pa nwọ́n ní ìbámu pẹ̀lú òfin; bẹ̃ni, àwọn ọmọ ogun Pákúsì nnì àti àwọn afọbajẹ nnì, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti gbé ohun ìjà-ogun ní ìdãbò bò orílè-èdè rẹ̀, ṣùgbọ́n tí yíò bã jà, ni a sì pa. Báyĩ sì ni ó di ohun tí ó tọ́ pé kí àwọn ará Nífáì ó pa òfin yĩ mọ́ fún ìpamọ́ orílẹ̀-èdè nwọn; bẹ̃ni, àti pé ẹnikẹ́ni tí a bá rí tí ó ntako òmìnira nwọn ni a pa ní kíákíá ní ìbámu òfin nã. Báyĩ sì ni ọgbọ̀n ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí; Mórónì àti Pahoránì sì ti dá àlãfíà padà sórí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, lãrín àwọn ènìyàn nwọn, nwọ́n sì ti pa gbogbo àwọn tí kò ṣe òtítọ́ sí ìjà òmìnira nã. Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, Mórónì mú kí a fi ìpèsè oúnjẹ ránṣẹ́ ní kíákíá, àti ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún mẹ́fà sí Hẹ́lámánì, láti ràn án lọ́wọ́ fún ìdãbò bò apá ilẹ̀ nã tí ó wà. Ó sì mú kí nwọ́n fi ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún mẹ́fà pẹ̀lú oúnjẹ tí ó tó, ránṣẹ́ sí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Léhì àti Tíákúmì. Ó sì ṣe tí nwọ́n ṣe èyí láti lè dãbò bò ilẹ̀ nã lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì. Ósì ṣe tí Mórónì àti Pahoránì, ti nwọ́n fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun sẹ́hìn ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nwọ́n kọjá lọ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun sí ilẹ̀ Nífáìhà, nítorítí nwọ́n pinnu láti lé àwọn ará Lámánì kúrò nínú ìlú-nlá nnì. Ó sì ṣe pé bí nwọ́n ṣe nrin ìrìnàjò nwọn lọ sínú ilẹ̀ nã, nwọ́n mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì pa nwọ́n, nwọ́n sì kó àwọn ìpèsè oúnjẹ nwọn àti àwọn ohun ìjà-ogun nwọn. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí nwọ́n ti mú nwọn, nwọ́n mú kí nwọ́n dá májẹ̀mú pé nwọn kò ní gbé ohun ìjà-ogun nwọn ti àwọn ará Nífáì mọ́. Nígbàtí nwọ́n sì ti dá májẹ̀mú yĩ tán nwọ́n rán wọn láti máa bá àwọn ará Ámọ́nì gbé, nwọ́n sì pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin tí í ṣe àwọn tí a kò pa. Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n ti rán nwọn jáde tán nwọ́n sì mú ìrìnàjò nwọn lọ sí apá ilẹ̀ Nífáìhà. Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n dé ìlú-nlá Nífáìhà, ni nwọ́n sì pàgọ́ nwọn sínú ọ̀dàn Nífáìhà, èyítí ó wà nítòsí ìlú-nlá Nífáìhà. Nísisìyí Mórónì ní ìfẹ́ kí àwọn ará Lámánì jáde wá láti bá nwọn jà, lori ọ̀dàn nã; ṣùgbọ́n nítorítí àwọn ará Lámánì mọ̀ nípa ìgboyà nlá tí nwọ́n ní, àti tí nwọ́n sì rí pípọ̀ tí nwọ́n pọ̀ púpọ̀, nítorínã nwọn kò jẹ́ jáde wá láti kọlũ nwọ́n; nítorínã nwọn kò jáde láti jà ní ọjọ́ nã. Nígbàtí alẹ́ sì lẹ́, Mórónì kọjá lọ nínú òkùnkùn alẹ́, ó sì wá sí órí odi ìlú nã láti ṣe amí apá ibitíàwọn ará Lámánì pàgọ́ sí pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn. Ó sì ṣe tí nwọ́n wà ní apá ìlà-oòrùn, lẹbá ọ̀nà àbáwọlé; nwọ́n sì nsùn. Àti nísisìyí ni Mórónì padà sí ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, ó sì mú kí nwọn ṣe àwọn okùn tí ó lágbára àti àwọn àkàbà, láti lè sọ̀ nwọ́n kalẹ̀ sínú ìlú láti orí odi ìlú nã. Ó sì ṣe tí Mórónì mú kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kọjá lọ kí nwọ́n lọ sí órí odi nã, kí nwọn ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi apá ìlú-nlá nã, bẹ̃ni, àní ní apá ìwọ̀-oòrùn, níbití àwọn ará Lámánì kò pàgọ́ sí pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn. Ó sì ṣe tí a sọ̀ gbogbo nwọn kalẹ̀ sínú ìlú-nlá nã ní òru, pẹ̀lú àwọn okùn nwọn tí ó lágbára àti àwọn àkàbà nwọn; báyĩ nígbàtí ilẹ̀ mọ́ gbogbo nwọn tí wà nínú odi ìlú-nlá nã. Àti nísisìyí, nígbàtí àwọn ará Lámánì jí tí nwọn sì ríi pé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì ti wà nínú odi-ìlú nwọn, ẹ̀rù bà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀, tóbẹ̃ tí nwọ́n sá jáde láti ẹnu ọ̀nà ìlú. Àti nísisìyí nígbàtí Mórónì ríi pé nwọ́n sálọ níwájú òun, ó mú kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sá tẹ̀lé nwọn, nwọ́n sì pa púpọ̀, nwọ́n sì ká ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ́, nwọ́n sì mú nwọn lẹ́rú; àwọn tí ó kù sì sá lọ sínú ilẹ̀ Mórónì, tí ó wà létí agbègbè bèbè òkun. Báyĩ s ì ni Mórónì à t i Pahoránì gba ìlú-nlá Nífáìhà ní áìpàdánù ẹ̀mí kankan; a sì pa púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì. Nísisìyí ó sì ṣe tí púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì tí nwọ́n kó lẹ́rú ní ìfẹ́ láti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ámọ́nì kí nwọ́n sì di ẹni òmìnira. Ó sì ṣe tí a fi fún gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ bẹ̃ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú nwọn. Nítorínã, gbogbo àwọn ará Lámánì tí a mú lẹ́rú sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ámọ́nì, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣiṣẹ́ kárakára, tí nwọ́n dáko, tí nwọn ngbin onírurú ọkà, àti àwọn onírurú agbo àti ọ̀wọ́ ẹran; báyĩ sì ni àwọn ará Nífáì rí ìtura gbà kúrò lọ́wọ́ àjàgà nlá; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi rí ìtura lórí gbogbo àwọn ará Lámánì tí nwọ́n mú lẹ́rú. Nísisìyí ó sì ṣe tí Mórónì, lẹ́hìn tí ó ti gba ìlú-nlá Nífáìhà, tí ó sì ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́rú, èyítí ó mú kí àwọn ẹgbẹ́ ogun Lámánì ó dínkù lọ́pọ̀lọpọ̀, àti lẹ́hìn tí ó ti gba àwọn ará Nífáì tí a ti mú lẹ́rú padà, tí nwọ́n sì fi agbára kún ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì lọ́pọ̀lọpọ̀; nítorínã Mórónì jáde lọ láti inú ilẹ̀ Nífáìhà lọ sínú ilẹ̀ Léhì. Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé Mórónì nbọ̀ wá kọlũ nwọ́n, ẹ̀rù tún bà nwọ́n, nwọ́n sì sálọ kúrò níwájú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì. Ó sì ṣe tí Mórónì àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sá tẹ̀lé nwọn láti ìlú-nlá dé ìlú-nlá, títí Léhì àti Tíákúmì fi bá nwọn pàdé; àwọn ará Lámánì nã sì sálọ kúrò níwájú Léhì àti Tíákúmì, àní títí dé etí agbègbè bèbè òkun, títí nwọn fi dé ilẹ̀ Mórónì. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì sì kójọ papọ̀, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi wà ní ọ̀kanṣoṣo nínú ilẹ̀ Mórónì. Nísisìyí Ámmórọ́nì,ọba àwọn ará Lámánì wà pẹ̀lú nwọn pẹ̀lú. Ó sì ṣe tí Mórónì àti Léhì àti Tíákúmì sì pàgọ́ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn yíká etí ilẹ̀ Mórónì, tóbẹ̃ tí nwọ́n yí àwọn ará Lámánì kákiri ní etí ilẹ̀ tí ó wà lẹba aginjù tí ó wà ní apá gũsù, àti ní etí ilẹ̀ tí ó wà lẹba aginjù tí ó wà ní apá ìlà-oòrùn. Báyĩ sì ni nwọ́n pàgọ́ ní alẹ́ ọjọ́ nã. Nítorí kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì kãrẹ̀ nítorí ìrìnàjò tí ó gùn tí nwọ́n rìn; nítorínã nwọn kò pinnu lé ọgbọ́n àrékérekè kankan nígbàtí alẹ́ lẹ́, àfi Tíákúmì; nítorítí ó bínú gidigidi sí Ámmórọ́nì, tóbẹ̃ tí ó fi rọ́ pé Ámmórọ́nì, àti Amalikíà arákùnrin rẹ̀, ni nwọ́n ti mú kí ogun nlá wà lãrín nwọn àti àwọn ará Lámánì, èyítí ó ti fa ogun àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ púpọ̀, bẹ̃ni, àti ìyàn púpọ̀. Ó sì ṣe tí Tíákúmì nínú ìbínú rẹ̀ nlá sì kọjá lọ sínú àgọ́ àwọn ará Lámánì, tí ó sì sọ ara rẹ̀ kalẹ̀ láti orí odi ìlú-nlá nã. Ó sì lọ pẹ̀lú okùn, láti ibìkan dé òmíràn, tóbẹ̃ tí ó sì rí ọba nã; ó sì ju ọ̀kọ̀ lũ, èyítí ó gun un lẹba ọkàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ọba nã jí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí ó tó kú, tóbẹ̃ tí nwọ́n sì sá tẹ̀lé Tíákúmì, tí nwọ́n sì pã. Nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Léhì àti Mórónì mọ̀ pé Tíákúmì ti kú nwọ́n banújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀; nítorí kíyèsĩ ó jẹ́ ẹnìkan tí ó ti jagun pẹ̀lú ìgboyà fún orílẹ̀-èdè rẹ̀, bẹ̃ni, ọ̀rẹ́ òdodo sí òmìnira; ó sì ti faradà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú tí ó pọ̀ púpọ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ó ti kú, ó sì ti lọ síbití gbogbo ayé nre. Nísisìyí ó sì ṣe tí Mórónì kọjá lọ ní ọjọ́ kejì, ó sì kọlũ àwọn ará Lámánì, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi pa nwọ́n ní ìpakúpa; tí nwọ́n sì lé nwọn kúrò lórí ilẹ̀ nã; nwọ́n sì sálọ, àní tí nwọn kò padà ní àkókò nã láti kọlũ àwọn ará Nífáì. Báyĩ sì ni ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin; báyĩ sì ni nwọ́n ní àwọn ogun àti ìtàjẹ̀sílẹ̀, àti ìyàn, àti ìpọ́njú, fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ìpànìyàn, ìjà, àti ìyapa sì ti wà, àti onírurú àìṣedẽdé, lãrín àwọn ènìyàn Nífáì; bíótilẹ̀ríbẹ̃ nítorí àwọn olódodo, bẹ̃ni, nítorí àdúrà àwọn olódodo, Ọlọ́run dá nwọn sí. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nítorí ogun ọjọ́ pípẹ́ tí ó wà lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì púpọ̀ nínú nwọn ti sé àyà nwọn le, nítorí ogun ọjọ́ pípẹ́ nã; púpọ̀ nínú nwọn sì rẹ ọkàn nwọn sílẹ̀ nítorí ìpọ́njú nwọn, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi rẹ ara nwọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, àní pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrẹra-ẹni sílẹ̀. Ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti fi agbára kún àwọn apá ilẹ̀ wọnnì èyítí ó ṣí sílẹ̀ sí àwọn ará Lámánì, títí ó fi ní ágbára tó, ó padà sínú ìlú-nlá Sarahẹ́múlà; Hẹ́lámánì pẹ̀lú sí padà sí ìlú-ìní rẹ; àlãfíà sì tún padà fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn Nífáì. Mórónì sì gbé ìdarí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ lé ọwọ́ ọmọ rẹ̀ ẹnití, orúkọ rẹ̀ njẹ Móróníhà; ó sì padà sí ilè ara rẹ̀ láti lè lo ìyókù ayé rẹ̀ ní àlãfíà. Pahoránì sì padà sí órí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀; Hẹ́lámánì sì gbà láti tún máa wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run síàwọn ènìyàn nã; nítorípé, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun àti ìjà ó ti di ohun tí ó yẹ láti tún fi ìlànà sílẹ̀ nínú ìjọ onígbàgbọ́. Nítorínã, Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ, láti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú agbára nlá sí ti yíyí ọkàn ènìyàn púpọ̀ padà kúrò nínú ìwà búburú nwọn, èyítí ó mú nwọn ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn àti láti rì wọn bọmi sí Olúwa Ọlọ́run nwọn. Ó sì ṣe tí nwọ́n tún fi ìjọ Ọlọ́run lélẹ̀, jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã. Bẹ̃ni, nwọ́n sì ṣe àwọn ìlànà nípa ti òfin. Nwọ́n sì yan àwọn onidajọ nwọn, àti àwọn onidajọ àgbà nwọn. Àwọn ènìyàn Nífáì sì tún bẹ̀rẹ̀sí ṣe rere lórí ilẹ̀ nã, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bí síi àti láti ní agbára púpọ̀ ní ilẹ̀ nã. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ní ọrọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n l’áìṣírò ọrọ̀ nwọn, tàbí agbára nwọn, tàbí ìlọsíwájú nwọn, nwọn kò gbé ara nwọn sókè nínú ìgbéraga; bẹ̃ sì ni nwọn kò lọ́ra láti rántí Olúwa Ọlọ́run nwọn; ṣùgbọ́n nwọ́n rẹ ara nwọn sílẹ̀ púpọ̀púpọ̀ níwájú rẹ̀. Bẹ̃ni, nwọ́n sì rántí àwọn ohun nlá tí Olúwa ti ṣe fún nwọn, pé ó ti gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ ikú, àti kúrò nínú ìdè, àti kuro nínú tũbú, àti kúrò lọ́wọ́ onírurú ìpọ́njú, ó sì ti gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn. Nwọ́n sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run nwọn láìsinmi, tóbẹ̃ tí Olúwa sì bùkún fún nwọn, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí nwọ́n fi ní agbára tí nwọ́n sì nṣe rere lórí ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí ohun gbogbo wọ̀nyí di ìmúṣẹ. Hẹ́lámánì sì kú, ní ọdún karundínlógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì. 63 Ṣíblọ́nì àti Hẹ́lámánì gba àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ nã—Àwọn ará Nífáì púpọ̀ rin ìrìnàjò lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá—Hágọ́tì kọ́ àwọn ọkọ̀ ojú omi, tí ó lọ sínú òkun ti apá ìwọ oòrùn—Móróníhà borí àwọn ará Lámánì ní ogun. Ní ìwọ̀n ọdún 56–52 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹrìndínlógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, tí Ṣíblọ́nì gba àwọn ohun mímọ́ nnì èyítí Álmà ti gbé fún Hẹ́lámánì. Ẹ̀nìti o tọ́ ni í sì í ṣe, ó sì rìn ní ìdúróṣinṣin níwájú Ọlọ́run; ó sì tẹramọ́ ṣíṣe èyítí ó dára títí, láti pa òfin Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ mọ́; arákùnrin rẹ̀ nã sì ṣe bẹ̃. Ọ́ sì ṣe tí Mórónì kú pẹ̀lú. Báyĩ sì ni ọdún kẹrìndínlógójì parí nínú ìjọba àwọn onídàjọ́. Ó sì ṣe ní ọdún kẹtàdínlógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí ọ̀pọlọpọ̀ àwọn ọmọ ogun, àní tí o tó ẹgbẹ̀rún marun àti irínwó pẹ̀lú àwọn ìyàwó nwọn àti àwọn ọmọ nwọn jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá. Ó sì ṣe tí Hágọ́tì, ẹnití í ṣe ọlọfintoto ènìyàn, nítorínã ni ó jáde lọ tí osì kọ́ ọkọ̀ ojú omi nlá kan fún ara rẹ̀, ní ibi ìpẹ̀kun ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, nítòsí ilẹ̀ Ibi-Ahoro, tí ó sì tĩ sínú omi tí ó wà ní apá ìwọ̀-oòrùn, ní ẹ̀bá ilẹ̀ tọ́ró èyítí ó já sí ilẹ̀ tí o wà ní apá àríwá. Ẹ kíyèsĩ, púpọ̀ nínú àwọn ará Nífáì ni ó wọ inú rẹ̀ lọ tí nwọn sì kó pẹ̀lú ìpèsè oúnjẹ tí ó pọ̀, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé; nwọ́n sì mú ìrìnàjò nwọn lọ sí apá àríwá. Báyĩ, sì ni ọdún kẹtàdínlógójì ṣe dópin. Àti ní ọdún kejìdínlógójì, ọkùnrin yĩ kọ́ àwọn ọkọ̀ míràn. Ọkọ̀ ìkínní nnì sì padà, àwọn ènìyàn púpọ̀ síi sì wọ inú rẹ̀; nwọ́n si kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèsè oúnjẹ, nwọ́n sì tún ṣíkọ̀ lọ sí ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá. Ó sì ṣe tí a kò gburo nwọn mọ́. Àwa sì rò wípé nwọ́n ti rì nínú ìsàlẹ̀ omi òkun ni. Ó sì ṣe tí ọkọ̀ míràn nã tún ṣíkọ̀ jáde lọ; àwa kò sì mọ́ ibití ó lọ sí. Ó sì ṣe nínú ọdún yìi kannã tí àwọn ènìyàn tí o kọjá lọ sí ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá pọ̀ púpọ̀. Báyĩ sì ni ọdún kejìdínlógójì parí. Ó sì ṣe ní ọdún kọkàndínlógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, Ṣíblọ́nì kú pẹ̀lú, Kọ̀ríántọ́nì sì ti jáde lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá nínú ọkọ̀, láti gbé ìpèsè oúnjẹ fún àwọn tí ó ti jáde lọ sínú ilẹ̀ nã. Nítorí ìdí èyí, ó jẹ́ èyítí ó yẹ fún Ṣíblọ́nì láti gbé àwọn ohun mímọ́ nnì, ṣãju ikú rẹ̀, lé ọwọ́ ọmọ Hẹ́lámánì, ẹnití í ṣe Hẹ́lámánì, tí a fi orúkọ bàbá rẹ̀ pè é. Nísisìyí kíyèsĩ, gbogbo àwọn ohun fífín nnì tí nwọ́n wà lọ́wọ́ Hẹ́lámánì ni a kọ jáde, tí a sì fi ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ ènìyàn jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã, àfi àwọn ibití Álmà ti pàṣẹ pé kí a máṣe fi ránṣẹ́ sí. Bíótilẹ̀ríbẹ̃ àwọn ohun wọ̀nyí ni nwọ́n níláti pamọ́ ní mímọ́, tí a sì gbé lé ọwọ́ nwọn láti ìran kan dé òmíràn; nítorínã nínú ọdún yìi, a ti gbé nwọ́n lé ọwọ́ Hẹ́lámánì kí Ṣíblọ́nì ó tó kú. Ó sì ṣe pẹ̀lú nínú ọdún yĩ tí àwọn olùyapa kan wà tí nwọn ti jáde lọ bá àwọn ará Lámánì; tí nwọ́n sì tún rú nwọn sókè nínú ìbínú sí àwọn ará Nífáì. Àti pẹ̀lú nínú ọdún yĩ kannã nwọ́n sọ̀kalẹ̀ wá pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun láti bá àwọn ará Móróníhà jagun, tàbí láti bá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Móróníhà jà, nínú èyítí nwọ́n nà nwọ́n, nwọn sì lé nwọ́n padà sínú ilẹ nwọn, tí nwọ́n sì pàdánù lọ́pọ̀lọpọ̀. Báyĩ sì ni ọdún kọkàndínlógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ará Nífáì dópin. Báyĩ sì ni a pari ọ̀rọ̀ nípa Álmà àti Hẹ́lámánì ọmọ rẹ̀, àti Ṣíblọ́nì pẹ̀lú, ẹnití í ṣe ọmọ rẹ̀. 1 Pahoránì kejì di adájọ́ àgbà, Kíṣkúmẹ́nì sì pã—Pákúmẹ́nì bọ́ sí órí ìtẹ́ ìdájọ́—Kóríántúmúrì ṣãjú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, ó mú Sarahẹ́múlà, ó sì pa Pákúmẹ́nì—Móróníhà borí àwọn ará Lámánì ó sì gba Sarahẹ́múlà padà, a sì pa Kóríántúmúrì. Ní ìwọ̀n ọdún 52 sí 50 kí a tó bí Olúwa wa. ÀTI nísisìyí kíyèsĩ, ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ogójì ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, ìṣòro nlá kan si bẹrẹ si wa lãrín àwọn ènìyàn ti ara Nífáì. Nítorí kíyèsĩ, Pahoránì ti kú, ó sì ti lọ sí ibi gbogbo ayé nrè; nítorínã asọ̀ líle sì bẹ̀rẹ̀sí wà nípa tani yíò gun ìtẹ́ ìdájọ́ lãrín àwọn arákùnrin nã, tí í ṣe ọmọ Pahoránì. Nísisìyí èyí ni orúkọ àwọn tí nwọ́n jà fún ìtẹ́ ìdájọ́, tí nwọ́n sì mú kí àwọn ènìyàn nã jà: Pahoránì, Pãnkì, àti Pákúmẹ́nì. Nísisìyí kĩ ṣe gbogbo àwọn ọmọ Pahoránì nìwọ̀nyí (nítorítí ó ní púpọ̀), ṣùgbọ́n àwọn yĩ ni àwọn tí nwọ́n jà fún ìtẹ́ ìdájọ́; nítorínã, nwọ́n sì mú ìyà sí ipa mẹ́ta kí ó wà lãrín àwọn ènìyàn nã. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó sì ṣe tí a yàn Pahoránì nípa ohùn àwọn ènìyàn nã láti jẹ́ adájọ́ àgbà àti olórí-ìlú lórí àwọn ènìyàn Nífáì. Ó sì ṣe tí Pákúmẹ́nì, nígbàtí ó ríi pé òun kò lè gba ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì darapọ̀ mọ́ ohùn àwọn ènìyàn nã. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Pãnkì, àti ẹ̀yà nínú àwọn ènìyàn nã tí ó ní ìfẹ́ pé kí ó di olórí-ìlú nwọn, bínú lọ́pọ̀lọpọ̀; nítorínã, ó sì ṣetán láti fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn mú àwọn ènìyàn nã láti rú sókè ní ìṣọ̀tẹ̀ sí àwọn arákùnrin nwọn. Ò sì ṣe bí ó ti fẹ́ ṣe eleyĩ, kíyèsĩ, nwọ́n múu, nwọ́n sì dá ẹjọ́ fún un gẹ́gẹ́bí ohùn àwọn ènìyàn nã, nwọ́n sì dájọ́ ikú fún un; nítorípé ó rú ìṣọ̀tẹ̀sí sókè ó sì lépa láti pa òmìnira àwọn ènìyàn nã run. Nísisìyí nígbàtí àwọn ènìyàn nnì tí nwọn fẹ́ kí ó jẹ̀ olórí-ìlú fún nwọn ríi pé a ti dájọ́ ikú fún un, nítorínã nwọ́n bínú, sì kíyèsĩ, nwọ́n rán ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Kíṣkúmẹ́nì lọ, àní lọ sí ìtẹ́ ìdájọ́ Pahoránì, o sì pa Pahoránì bí ó ṣe joko lórí ìtẹ́ ìdájọ́. Àwọn ìránṣẹ́ Pahoránì sì sá tẹ̀lée; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, eré tí Kíṣkúmẹ́nì sá pọ̀ púpọ̀ tó bẹ̃ tí ẹnìkẹ́ni kò lè lée bá. Ó sì lọ sí ọ́dọ̀ àwọn tí ó rán an, gbogbo nwọ́n sì bá ara nwọn dá májẹ̀mú, bẹ̃ni, nwọ́n sì búra pẹ̀lú Ẹlẹ́da ayérayé nwọn, pé nwọn kò ní sọ fún ẹnìkẹ́ni pé Kíṣkúmẹ́nì ni ó pa Pahoránì. Nítorínã, a kò mọ́ Kíṣkúmẹ́nì lãrin àwọn ènìyàn Nífáì, nítorítí ó bò ojú ara rẹ̀ ní ìgbàtí ó lọ pa Pahoránì. Kíṣkúmẹ́nì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí nwọ́n ti bã dá májẹ̀mú, sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyànnã, ní ọ̀nà tí nwọn kò fi lè rí nwọn mú; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí nwọ́n rí mú ni nwọ́n dájọ́ ikú fún. Àti nísisìyí sì kíyèsĩ, a yan Pákúmẹ́nì gẹ́gẹ́bí ohùn àwọn ènìyàn nã, láti jẹ́ adájọ́-àgbà àti olórí-ìlú lórí àwọn ènìyàn nã, láti jọba rọ́pò arákùnrin rẹ̀ tí í ṣe Pahoránì; ó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀tọ́ rẹ̀. Gbogbo eleyĩ ni a sì ṣe ní ogojì ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́; ó sì ní òpin. Ó sì ṣe ní ọdún kọkànlélógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí àwọn ará Lámánì kó àìníye ẹgbẹ ọmọ-ogun jọ, tí nwọ́n sì di ìhámọ́ra ogun fún nwọn pẹ̀lú idà, àti símẹ́tà àti ọrun, àti ọfà, àti ìborí, àti ìgbàyà-ogun, àti pẹ̀lú onírũrú apata lóríṣiríṣi. Nwọ́n sì tún sọ̀kalẹ̀ wá láti gbógun ti àwọn ará Nífáì. Ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ í ṣe Kóríántúmúrì ni ó sì ṣãjú nwọn; ó sì jẹ́ àtẹ̀lé Sarahẹ́múlà; ó sì jẹ́ olùyapa kúrò lãrín àwọn ará Nífáì; ènìyàn títóbi tí ó sì lágbára ní í ṣe. Nítorínã, ọba àwọn ará Lámánì, ẹnití orúkọ rẹ̀ í ṣe Túbálọ́tì, tí í ṣe ọmọ Ámmórọ́nì, lérò wípé Kóríántúmúrì, nítorítí ó jẹ́ alágbára ènìyàn, yíò lè dojúkọ àwọn ará Nífáì, pẹ̀lú agbára rẹ̀ àti pẹ̀lú ọgbọ́n nlá rẹ̀, tóbẹ̃ tí yíò borí àwọn ará Nífáì bí òun bá rán an lọ— Nítorínã, ó rú nwọn sókè ní ìbínú, ó sì kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó sì yan Kóríántúmúrì láti jẹ́ olórí nwọn, ó sì mú kí nwọn ó kọjá lọ sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà láti dojúkọ àwọn ará Nífáì. Ó sì ṣe nítorípé asọ̀ púpọ̀ àti ìṣòro púpọ̀ wà nínú ìjọba nã, tí nwọn kò ní àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó pọ̀ tó ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; nítorítí nwọ́n ti rò pé àwọn ará Lámánì kò lè dábá láti wọ inú ilẹ̀ nwọn wá láti kọlũ ìlú-nlá Sarahẹ́múlà títóbi nnì. Ṣùgbọ́nósì ṣe tíKóríántúmúrì sì kọjá lọ níwájú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ nlá, tí nwọn sì kọlu àwọn tí ngbé inú ìlú-nlá nã, ìrìn nwọn sì yá tóbẹ̃ tí kò sí àkokò fún àwọn ará Nífáì láti kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn jọ. Nítorínã Kóríántúmúrì ké àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà ìlúnã lulẹ̀, ó sì kọjá lọ pẹ̀lú gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sínú ìlú-nlá nã, nwọ́n sì pa gbogbo àwọn tí ó takò nwọ́n, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi mú ìlú-nlá nã pátápátá. Ó sì ṣe tí Pákúmẹ́nì, ẹnití í ṣe adájọ́-àgbà, sí sá níwájú Kóríántúmúrì, àní lọ sí ibi odi ìlú-nlá nã. Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì lù ú mọ́ ara ògiri nã, tóbẹ̃ tí ó fi kú. Báyĩ sì ni ọjọ́ ayé Pákúmẹ́nì ṣe parí. Àti nísisìyí nígbàtí Kóríántúmúrì ríi pé òun ti mú ìlú-nlá Sarahẹ́múlà nã, tí ó sì ríi pé àwọn ará Nífáì ti sá níwájú nwọn, tí a sì pa nwọ́n tí a sì ti mú nwọn, tí a sì ti jù nwọ́n sínú tũbú, àti pé òun ti mú ibi-ìsádi nwọn tí ó lágbára jù ní ìní ní gbogbo ilẹ̀ nã, ó ní ìgboyà tóbẹ̃ tí ó ṣetán láti jáde lọ láti kọlũ gbogbo ilẹ̀ nã. Àti nísisìyí kò sì dúró nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ṣùgbọ́n ó kọjá lọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun nlá kan, àní sí ìhà ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀; nítorípé ó jẹ́ ìpinnu rẹ̀ láti lọ kí ó sì fi idà gba ilẹ̀ nã, kí ó lè gba àwọn ilẹ̀ nã tí ó wà ní apá àríwá. Àti pé ó lérò wípé inú ãrin ilẹ̀ nã ni agbára nwọn pọ̀ sí, nítorínã ó kọjá lọ, tí kò sì fún nwọn lãyè láti kó ara nwọn jọ bíkòṣe ní ọ̀wọ́ kékèké; ní ipò yĩ ni nwọ́n sì ṣe kọlù nwọ́n tí nwọ́n sì ké nwọn lulẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ogun Kóríántúmúrì yĩ tí ó mú kọjá lọ sí ãrin inú ilẹ̀ nã fún Móróníhà ní ànfãní púpọ̀ lórí nwọn, l’áìṣírò bí àwọn ará Nífáì tí nwọ́n ti pa ti pọ̀ tó. Nítorí kíyèsĩ, Móróníhà ti rò wípé àwọn ará Lámánì kò lè dábã láti wá sínú ãrin ilẹ̀ nã, ṣùgbọ́n pé nwọn yíò kọlũ àwọn ìlú-nlá tí ó wà ní agbègbè etí ilẹ̀ nã gẹ́gẹ́bí nwọ́n ti í ṣe tẹ́lẹ̀rí; nítorínã ni Móróníhà ṣe mú kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn tí ó lágbára dábọ́ bò àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní agbègbè etí ilẹ̀ nã. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì kò ní íbẹ̀rù gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n nwọ́n ti wá sínú ãrin ilẹ̀ nã nwọ́n sì ti gba olú-ìlú ilẹ̀ nã èyítí i ṣe ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, nwọ́n sì nkọjá lọ sí àwọn ibití ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ilẹ̀ nã, tí nwọ́n sì npa àwọn ènìyàn nã ní ìpakúpa, àwọn ọkùnrin, àti àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé, tí nwọ́n sì ngba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibi ìsádi. Ṣùgbọ́n nígbàtí Móróníhà ti rí èyí, lójúẹsẹ̀ ni ó rán Léhì lọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan kãkiri láti lọ ṣãjú nwọn kí nwọn ó tó dé ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀. Báyĩ ni ó sì ṣe; ó sì ṣãjú nwọn kí nwọn ó tó dé ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, ó sì bá nwọn jagun, tóbẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí sá padà sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Ó sì ṣe tí Móróníhà bọ́ síwájú nwọn nínú sísá padà nwọn, tí ó sì bá nwọn jagun, tóbẹ̃ tí ó di ogun tí ó gbóná lọ́pọ̀lọpọ̀; bẹ̃ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni nwọ́n pa, nínú àwọn tí nwọ́n pa ni a ti rí Kóríántúmúrì. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì kò lè sá padà lọ́nà kan tàbí òmíràn, bóyá ní apá àríwá, tàbí ní apá gũsù, tàbí ní apá ìlà oòrùn, tàbí ní apá ìwọ oòrùn, nítorítí àwọn ará Nífáì yí nwọn ká ní gbogbo ìhà. Báyĩ sì ni Kóríántúmúrì ṣe tí ó lé àwọn ará Lámánì sí ãrin àwọn ará Nífáì tóbẹ̃ tí nwọ́n fi wà ní ìkáwọ́ agbára àwọn ará Nífáì, tí nwọ́n sì pa òun tìkararẹ̀, tí àwọn ará Lámánì sì jọ̀wọ́ ara nwọn lé àwọn ará Nífáì lọ́wọ́. Ó sì ṣe tí Móróníhà tún gba ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, tí ó sì mú kí àwọn ará Lámánì tí nwọ́n ti kó lẹ́rú ó jáde kúrò lórí ilẹ̀ nã ní àlãfíà. Báyĩ sì ni ọdún kọkànlélógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ dópin. 2 Hẹ́lámánì, ọmọ Hẹ́lámánì, di onidajọ-àgbà—Gádíátónì jẹ́ olùdarí fún ẹgbẹ́ Kíṣkúmẹ́nì—Ìránṣẹ́ Hẹ́lámánì pa Kíṣkúmẹ́nì, àwọn ẹgbẹ́ Gádíátónì sì sálọ sínú aginjù. Ní ìwọ̀n ọdún 50 sí 49 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe ní ọdún kejìlélógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, lẹ́hìn tí Móróníhà ti tún fi àlãfíà lélẹ̀ lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì, kíyèsĩ kò sí ẹnití yíòbọ́ sí órí ìtẹ́ ìdajọ́; nítorínã ni asọ̀ tún bẹ̀rẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn nã lórí ẹnití yíò bọ́ sí órí ìtẹ́ ìdájọ́. Ó sì ṣe tí a yan Hẹ́lámánì, ẹnití í ṣe ọmọ Hẹ́lámánì, láti bọ́ sí órí ìtẹ́ ìdájọ́, nípa ohùn àwọn ènìyàn nã. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Kíṣkúmẹ́nì, ẹnití ó pa Pahoránì dúró ní ìkọ̀kọ̀ láti pa Hẹ́lámánì pẹ̀lú; àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ sì tĩ lẹ́hìn, àwọn tí nwọ́n ti dá májẹ̀mú pé ẹnìkẹ́ni kò ní mọ́ ohun búburú tí ó ṣe. Nítorítí ẹnìkan wà tí orúkọ rẹ̀ í ṣe Gádíátónì, tí ó já fáfá nínú ọ̀rọ̀ sísọ, àti ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, láti tẹ̀ síwájú nínú ìwà ìpànìyàn àti olè jíjà ní ìkọ̀kọ̀; nítorínã ó di olórí fun ẹgbẹ́ Kíṣkúmẹ́nì. Nítorínã ó ntàn wọ́n, àti Kíṣkúmẹ́nì pẹ̀lú, pé bí nwọ́n bá fi òun sí órí ìtẹ́ ìdájọ́ òun yíò jẹ́ kí nwọn ó fi àwọn tí ó wà nínú ẹgbẹ́ òun sí ipò agbára àti àṣẹ lãrín àwọn ènìyàn nã; nítorínã Kíṣkúmẹ́nì lépa láti pa Hẹ́lámánì. Ó sì ṣe bí ó ṣe nlọ sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́ láti pa Hẹ́lámánì, kíyèsĩ ọ̀kan nínúàwọn iranṣẹHẹ́lámánì, tí ó ti jáde ní ìbojú ní òru, tí ó sì ti fi ète gba imọ nípa àwọn èwé tí ẹgbẹ́ yĩ ti wé láti pa Hẹ́lámánì— Ó sì ṣe tí ó bá Kíṣkúmẹ́nì pàdé, ó sì fún un ní àmì kan; nítorínã Kíṣkúmẹ́nì fi ìfẹ́ inú rè hàn fun un; sì fẹ́ kí ó mú òun lọ sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́ kí ó lè pa Hẹ́lámánì. Nígbàtí ìránṣẹ́ Hẹ́lámánì nã sì ti mọ́ gbogbo ohun tí ó wà ní ọ́kàn Kíṣkúmẹ́nì, àti bí ó ṣe jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ láti pànìyàn, ati pẹ̀lú pé ìfẹ́ gbogbo àwọn tí ó wà nínú ẹgbẹ́ rẹ̀ ni láti pànìyàn, àti láti jalè, àti láti gba agbára, (èyí sì ni ète òkùnkùn wọn, àti ẹgbẹ wọn) ìránṣẹ́ Hẹ́lámánì nã sọ fún Kíṣkúmẹ́nì pé: Jẹ́ kí àwa ó lọ sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́ nã. Nísisìyí èyí s ì dùn mọ́ Kíṣkúmẹ́nì nínú gidigidi, nítorítí ó lérò wípé òun yíò mú èté òun di síṣe; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìránṣẹ́ Hẹ́lámánì nã, bí nwọ́n ṣe nlọ sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́ nã, ni ó sì gún Kíṣkúmẹ́nì lọ́bẹ àní ní ọkàn rẹ̀, tí ó sì ṣubú lulẹ̀ láìkérora. Ó sì sáré lọ sọ fún Hẹ́lámánì àwọn ohun tí ó ti rí, àti tí ó ti gbọ́, àti tí ó ti ṣe. Ó sì ṣe tí Hẹ́lámánì ránṣẹ́ jáde pé kí nwọn ó mú ẹgbẹ́ àwọn olè àti apànìyàn ìkọ̀kọ̀ wọ̀nyí, pé kí a lè pa nwọ́n ní ìbámu pẹ̀lú òfin. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nígbàtí Gádíatónì ti ríi pé Kíṣkúmẹ́nì kò padà mọ́ ẹ̀rù bã pé nwọn yíò pãrun; nítorínã ó mú kí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé oun. Nwọ́n sì sá jáde kúrò ní ilẹ̀ nã, ní ọ̀nà ìkọ̀kọ̀, sínú aginjù; báyĩ ni ó sì rí nígbàtí Hẹ́lámánì ránṣẹ́ jáde láti mú àwọn ènìyàn nã a kò rí nwọn níbikíbi. A ó sì sọ síwájú síi nípa Gádíátónì yĩ lẹ́hìn èyí. Báyĩ sì ni ọdún kejìdínlógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí. Sì kíyèsĩ, ní òpin ìwé yĩ ẹ̀yin ó ríi pé Gádíátónì yĩ ni ó bí ìsubú nã, bẹ̃ni, èyítí ó fẹ́rẹ̀ fa ìparun àwọn ènìyàn Nífáì pátápátá. Kíyèsĩ èmi kò sọ wípé òpin ìwé Hẹ́lámánì, ṣùgbọ́n mo wípé òpin ìwé Nífáì, nínú èyítí mo ti mú gbogbo àkọsílẹ̀ tí èmi ti kọ. 3 Àwọn ará Nífáì púpọ̀ ṣí lọ sí ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá—Nwọ́n kọ́ ilé amọ̀ líle nwọ́n sì kọ àwọn àkọsílẹ̀ púpọ̀—Ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ni a yípadà tí a sì rìbọmi—Ọ̀rọ̀Ọlọ́run nií darí ènìyàn sí ìgbàlà—Nífáì ọmọ Hẹ́lámánì bọ́ sí órí ìtẹ́ ìdájọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 49 sí 39 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ọdún kẹtàlélógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, kò sí ìjà lãrín àwọn ènìyàn Nífáì àfi fún ìgbéraga díẹ̀ tí ó wà nínú ìjọ nã, èyítí ó mú kí ìyapa díẹ̀ wà lãrín àwọn ènìyàn nã, àwọn ohun wọ̀nyí ni nwọ́n sì ṣe àtúnṣe rẹ̀ nígbàtí ọdún kẹtàlélógójì nparí lọ. Kò sì sí asọ̀ lãrín àwọn ènìyàn nã nínú ọdún kẹrìnlélógójì; bákannã ni kò sì sí asọ̀ púpọ̀ nínú ọdún karundinlãdọta. Ó sì ṣe ní ọdún kẹrìndínlãdọ́ta, bẹ̃ni, asọ̀ púpọ̀ wà àti ìyapa púpọ̀; nínú èyítí àwọn tí ó jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà pọ̀ púpọ̀, tí nwọ́n sì lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá láti múu ní ìní. Nwọ́n sì rin ìrìnàjò tí ó jìnà púpọ̀púpọ̀, tóbẹ̃ tí nwọ́n dé ibití àwọn omi nlá-nlá àti àwọn odò púpọ̀púpọ̀ wà. Bẹ̃ni, àní nwọ́n tàn ká gbogbo ilẹ̀ nã, sí ibikíbi tí nwọn kò í sọ di ahoro àti tí kò ní igi, nítorí àwọn tí nwọ́n ti ngbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀rí tí nwọ́n sì ti jogún ilẹ̀ nã. Àti nísisìyí kò sí apá ilẹ̀ nã tí ó wà ní ahoro, bíkòṣe fún igi; ṣùgbọ́n nítorí bí ìparun àwọn ènìyàn tí ó ngbé ilẹ̀ nã tẹ́lẹ̀rí ti pọ̀ tó nwọn npẽ ní ahoro. Nítorítí igi díẹ̀ ni ó sì wà lórí ilẹ̀ nã, bíótilẹ̀ríbẹ̃ àwọn ènìyàn nã tí ó jáde lọ di olùjáfáfá nínú lílo amọ̀ líle; nítorínã nwọ́n sì kọ́ ilé amọ̀ líle, nínú èyítí nwọ́n gbé. Ó sì ṣe tí nwọ́n pọ̀ síi tí nwọ́n sì tàn kálẹ̀, nwọ́n sì kọjá lọ láti ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù lọ sí ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá, nwọ́n sì tàn kálẹ̀ tóbẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí bò orí gbogbo ilẹ̀ ayé, láti òkun tí ó wà ní apá gũsù, títí dé òkun tí ó wà ní apá àríwá, láti òkun tí ó wà ní apá ìwọ oòrùn títí dé òkun tí ó wà ní apá ìlà oòrùn. Àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ apá àríwá sì ngbé inú àgọ́, àti nínú àwọn ilé amọ̀ líle, nwọ́n sì jẹ́ kí igi èyíkéyĩ tí ó bá hù jáde nínú ilẹ̀ nã kí ó dàgbà, pé láìpẹ́ àwọn yíò ní igi láti kọ́ àwọn ilé wọn, bẹ̃ni, awọn ìlú-nlá nwọn, àti àwọn tẹ́mpìlì nwọn, àti àwọn sínágọ́gù nwọn, àti àwọn ibimímọ́ nwọn, àti onirũru àwọn ilé kíkọ́ nwọn. Ó sì ṣe bí igi ti ṣe ọ̀wọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá, nwọ́n sì kó púpọ̀ wọlé nípa ọ̀kọ̀-omi. Báyĩ sì ni nwọ́n mú kí ó ṣeéṣe fún àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ apá àríwá láti lè kọ́ ìlú-nlá púpọ̀púpọ̀, pẹ̀lú igi àti pẹ̀lú amọ̀ líle. Ó sì ṣe tí púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn Ámọ́nì, tí nwọ́n jẹ́ ará Lámánì nípa bíbí, sì lọ pẹ̀lú sínú ilẹ̀ yĩ. Àti nísisìyí àwọn àkọsílẹ̀ tí nwọ́n kọ nípa àwọn ènìyàn yìi pọ̀ púpọ̀, láti ọwọ́ púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn yĩ, àwọn èyítí ó wà pàtó àti tí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nípa nwọn. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìdá kan nínú ọgọrun àwọn ìṣe àwọn ènìyàn yĩ, bẹ̃ni àkọsílẹ̀ nípa àwọn ará Lámánì, àti nípa àwọn ará Nífáì, àti àwọn ogun nwọn, àti ìjà, àti ìyapa, àti ìwãsù nwọn, àti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ nwọn, àti lílo ọkọ̀-omi nwọn àti kikan ọkọ-omi nwọn, àti kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì wọn, àti ti sinagọgu, àti àwọn ibi-mímọ́ nwọn, àti ìwà òdodo nwọn, àti ìwà búburú nwọn, àti ìwà ìpànìyàn nwọn, àti àwọn olè jíjà nwọn, àti àwọn ìkógun nwọn, àti onírurú ìwà ẽrí nwọn àti ìwà àgbèrè nwọn, ni kò lè gba inu iṣẹ́ yĩ. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àti àwọn àkọsílẹ̀ ní onírurú ni ó wà, tí àwọn ará Nífáì ní pàtàkì ti kọ sílẹ̀. Tí nwọ́n sì ti fi lé ara nwọn lọ́wọ́ láti ọwọ́ àwọn ará Nífáì láti ìrán kan dé òmíràn, àní títí nwọ́n fi ṣubú sínú ìwàìrékọjá tí a sì ti pa nwọ́n, tí a ti ṣe ìkógun nwọn, tí a dọdẹ nwọn, ti a sì lé nwọn jáde, tí a pa nwọ́n, tí a sì tú nwọn ká lórí ilẹ̀ ayé, tí nwọ́n sì dàpọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì títí a kò fi pè nwọ́n ní ará Nífáì mọ́, tí nwọ́n sì di ènìyàn búburú, àti ẹhànnà ènìyàn, àti oníkà ènìyàn, bẹ̃ni, àní tí nwọ́n di àwọn ará Lámánì. Àti nísisìyí èmi tún padà sí órí ọ̀rọ̀ mi; nítorínã, ohun tí èmi ti sọ ti rí bẹ̃ lẹ́hìn tí asọ̀ nlá, àti ìrúkèrúdò, àti ogun, àti ìyapa, ti wà lãrín àwọn ará Nífáì. Ọdún kẹrìndínlãdọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ dópin; Ó sì ṣe tí asọ̀ nlá sì tún wà nínú ilẹ̀ nã, bẹ̃ni, àní ní ọdún kẹtàdínlãdọ́ta, àti ní ọdún kejìdínlãdọ́ta. Bíótilẹ̀ríbẹ̃ Hẹ́lámánì ṣe ìtẹ́ ìdajọ́ pẹ̀lú àìṣègbè àti ìṣòtítọ́; bẹ̃ni, ó gbìyànjú láti pa àwọn ìlànà, àti àwọn ìdajọ́ àti àwọn òfin Ọlọ́run mọ́; ó sì tẹramọ́ èyítí ó tọ́ níwájú Ọlọ́run; ó sì nrìn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà bàbá rẹ̀, tóbẹ̃ tí ó sì ṣe rere lórí ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí ó ní ọmọ méjì. Ó sọ ọmọ rẹ̀ èyítí í ṣe àkọ́bí ní Nífáì, èyítí ó kéré jù ni ó sì sọ ní Léhì. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà fún iṣẹ́ Olúwa. Ó sì ṣe tí àwọn ogun àti àwọn asọ̀ bẹ̀rẹ̀sí dáwọ́dúró, ní díẹ̀díẹ̀, lãrín àwọn ènìyàn ará Nífáì, nígbàtí ọdún kejìdínlãdọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì fẹ́rẹ̀ dópin. Ó sì ṣe ní ọdún kọkàndínlãdọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, àlãfíà sì wà nínú ilẹ̀ nã, àfi fún àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn tí Gádíátónì olè nnì ti dá sílẹ̀ ní àwọn apá ilẹ̀ nã níbití àwọn ènìyàn ti tẹ̀dósí púpọ̀púpọ̀, èyítí kò hàn sí àwọn tí í ṣe olórí ìjọba nã ní àkokò nã; nítorínã ni a kò ṣe pa nwọ́n run tán ní ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe ní ọdún yĩ kannã ìlọsíwájú tí ó pọ̀ wà nínú ìjọ nã; tóbẹ̃ tí ẹgbẹ̃gbẹ̀rún fi darapọ̀ mọ́ ìjọ nã tí nwọ́n ṣe ìrìbọmi sí ìrònúpìwàdà. Bẹ̃ ni ìlọsíwájú ìjọ nã sì pọ̀ tó, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún tí a dà lé orí àwọn ènìyàn nã, tóbẹ̃ tí ẹnu ya àwọn olórí àlùfã àti àwọn olùkọ́ni rékọjá. Ó sì ṣe tí iṣẹ́ Olúwa sì tẹ̀síwájú tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ṣe ìrìbọmi tí nwọ́n sì darapọ̀ mọ́ ìjọ Ọlọ́runnã, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn, bẹ̃ni, àní ẹgbẹ̃gbẹ̀rún. Báyĩ ni àwa lè ríi pé alãnú ni Olúwa sí àwọn tí yíò pe orúkọ rẹ̀ mímọ́ pẹ̀lú òtítọ́-inú. Bẹ̃ni, báyĩ ni àwa ríi pé ẹnu ọ̀nà ọ̀run ṣí sílẹ̀ sí ènìyàn gbogbo, àní sí àwọn tí yíò gba orúkọ Jésù Krístì gbọ́, ẹnití í ṣe Ọmọ Ọlọ́run. Bẹ̃ni, àwa ríi pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá fẹ́ lè di ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú, èyítí ó yè, tí ó sì ní agbára, tí yíò sì pín pátápátá gbogbo ẹ̀tàn àti ìkẹ́kùn àti ọgbọ́n àrékérekè èṣù nnì, tí yíò sì darí ẹnití ó gba Krístì gbọ́ ní ipa ọ̀nà èyítí ó há tí ó sì ṣe tẹ̃rẹ́ lórí ọ̀gbun ìbànújẹ́ ayérayé èyítí a ti pèsè sílẹ̀ láti gbé àwọn ènìyàn búburú mì— Tí yíò sì mú ẹ̀mí nwọn, bẹ̃ni, ẹ̀mí àìkú nwọn, sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run nínú ìjọba ọ̀run, láti joko pẹ̀lú Ábráhámù, àti Ísãkì, àti pẹ̀lú Jákọ́bù àti pẹ̀lú àwọn bàbá wa mímọ́, tí nwọn kò sì ní jáde mọ́. Àti nínú ọdún yĩ ayọ̀ sì wà nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti ní gbogbo agbègbè tí ó yĩ ka, àní ní gbogbo ilẹ̀ ti àwọn ará Nífáì ní ní ìní. Ó sì ṣe tí àlãfíà àti ayọ̀ tí ó pọ̀ púpọ̀ wà ní ìyókù ọdún kọkàndínlãdọ́ta nã; bẹ̃ni, àti pé àlãfíà àti ayọ̀ tí ó pọ̀ púpọ̀ wà síbẹ̀ síi ní àkokò ãdọ́ta ọdún nã nínú ìjọba àwọn onídàjọ́. Àti pé ní ọdún kọkànlélãdọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ àlãfíà sì wà pẹ̀lú, àfi fún ìwà ìgbéraga èyítí ó bẹ̀rẹ̀sí wọ inú ìjọ nã—kì í ṣe nínú ìjọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ọkàn àwọn ènìyàn tí nwọn njẹ́wọ́ pé àwọn wà nínú ìjọ Ọlọ́run— Nwọ́n sì gbé ara nwọn sókè nínú ìgbéraga, àní ní inúnibíni sí púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin nwọn. Nísisìyí èyí yĩ sì jẹ́ ohun búburú nlá, èyítí ó mú ki wọ́n ṣe inúnibíni púpọ̀ sí àwọn tí í ṣe onírẹ̀lẹ̀ nínú àwọn ènìyàn nã, àti kí nwọn ó la ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọnjú kọjá. Bíótilẹ̀ríbẹ̃ nwọ́n gbàdúrà nwọ́n sì gba ãwẹ̀ nígbà-kũgbà, nwọ́n sì túbọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ síi, nwọ́n sì túbọ̀ dúró ṣinṣin síi nínú ìgbàgbọ́ nwọn nínú Krístì, títí ọkàn nwọn fi kún fún ayọ̀ àti ìtùnú, bẹ̃ni, àní títí dé ìwé-mímọ́ àti ìsọdimímọ́ ọkàn nwọn, ìsọdimímọ́ èyítí nbá nwọn nítorítí nwọn jọ̀wọ́ ọkàn nwọn sílẹ̀ fún Ọlọ́run. Ó sì ṣe tí ọdún kejìlélãdọ́ta parí ní àlãfíà pẹ̀lú, àfi fún ìgbéraga nlá èyítí ó ti wọ inú ọkàn àwọn ènìyàn nã lọ; èyí sì rí bẹ̃ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ nwọn àti ìlọsíwájú nwọn ní ilẹ̀ nã; ó sì ndàgbà nínú nwọn lójojúmọ́. Ó sì ṣe ní ọdún kẹtàlélãdọta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, Hẹ́lámánì sì kú, ọmọ rẹ̀ àkọ́bí Nífáì sì bẹ̀rẹ̀sí jọba ní ipò rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó nṣe ìtẹ́ ìdajọ́ pẹ̀lú àìṣègbè àti ìṣòtítọ́; bẹ̃ni, ó sì npa òfin Ọlọ́run mọ́, ó sì nrìn ní ọ̀nà bàbá rẹ̀. 4 Àwọn tí ó ti yapa kúrò lára àwọn ará Nífáì darapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì láti mú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà—Ìṣubú bá àwọn ará Nífáì nítorí ìwà búburú nwọn—Ìjọ nã sì nrẹ̀hìn,àwọn ènìyàn nã sì di aláìlágbára gẹ́gẹ́bí àwọn ará Lámánì. Ní ìwọ̀n ọdún 38 sí 30 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe ní ọdún kẹrìnlélãdọ́ta tí ìyapa púpọ̀ wà nínú ìjọ nã, asọ̀ sì wà lãrín àwọn ènìyàn nã pẹ̀lú, tóbẹ̃ tí ìtàjẹ̀sílẹ̀ púpọ̀ fi wà. A sì pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn nã a sì lé nwọn jáde kuro lórí ilẹ̀ nã, nwọ́n sì tọ ọba àwọn ará Lámánì lọ. Ó sì ṣe tí nwọ́n sì gbìyànjú láti ru àwọn ará Lámánì sókè láti kọlũ àwọn ará Nífáì nínú ogun; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì bẹ̀rù gidigidi, tóbẹ̃ tí nwọn kò fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn olùyapa nã. Ṣubọ́n ó sì ṣe ní ọdún kẹrìndínlọ́gọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí àwọn olùyapa tí ó kúrò lára àwọn ará Nífáì lọ sí ọ́dọ̀ àwọn ará Lámánì; tí nwọ́n sì ní àṣeyọrí pẹ̀lú àwọn míràn nì láti ru nwọn sókè ní ìbínú sí àwọn ará Nífáì; nwọ́n sì fi gbogbo ọdún nã ṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun. Àti ní ọdún kẹtàdínlọ́gọ́ta nwọn sì sọ̀kalẹ̀ wá láti bá àwọn ará Nífáì jagun, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ṣí ípa ènìyàn; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí ó fi jẹ́ wípé ní ọdún kejìdínlọ́gọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ nwọ́n ní àṣeyọrí láti mú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; bẹ̃ni, àti ilẹ̀ gbogbo, àní títí dé ilẹ̀ èyítí ó wà nítòsí ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀. Nwọ́n sì lé àwọn ará Nífáì àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Móróníhà àní sínú ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀; Níbẹ̀ ni nwọ́n sì dãbò bò ará nwọn lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì, láti apá òkun ti apá ìwọ oòrùn, àní títí dé ti apá ìlà-oòrùn; èyítí í ṣe ìrìnàjò ọjọ́ kan fún ará Nífáì láti rìn, ní ãlà tí nwọ́n ti mọdisí tí nwọ́n sì ti fi àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn sí láti dãbò bò orílẹ̀-èdè nwọn tí ó wà ní apá àríwá. Báyĩ sì ni àwọn olùyapa-kúrò lára àwọn ará Nífáì, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, gba gbogbo ohun ìní àwọn ará Nífáì tí ó wà nínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá gúsù. Gbogbo èyíi ni nwọ́n sì ṣe nínú ọdún kejìdínlọ́gọ́ta àti ọdún kọkàndínlọ́gọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́. Ó sì ṣe nínú ọgọ́ta ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí Móróníhà sì ní àṣeyọrí pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ láti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, nwọ́n gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá padà èyítí ó ti bọ́ sí ọwọ́ àwọn ará Lámánì tẹ́lẹ̀. Ó sì ṣe ní ọdún kọkànlélọ́gọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ tí nwọ́n ní àṣeyọrí láti gbà àní ìdajì ìní nwọn padà. Nísisìyí àdánù nlá àwọn ará Nífáì yĩ, àti ìpànìyàn nlá èyítí ó wà lãrín nwọn, kì bá ti rí bẹ̃ bí kò bá ṣe nítorí ìwà búburú àti ìwà ẹ̀gbin èyítí ó wà lãrín nwọn; bẹ̃ni, ó sì wà lãrín àwọn tí ó njẹ́wọ́ pé àwọn wà nínú ìjọ Ọlọ́run. Àti pé nítorípé nwọ́n ní ìgbéraga nínú ọkàn nwọn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ nwọn, bẹ̃ni, nítorí ìfìyàjẹ àwọn tálákà, tí nwọ́n sì háwọ́ oúnjẹ mọ́ ẹnití ebi npa, tí nwọ́n sì háwọ́ aṣọ mọ́ ẹnití ó wà ní ìhòhò, tí nwọ́n sì gbá àwọn arákùnrin nwọn tí í ṣe onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́, tí nwọ́n sì fi àwọn ohun mímọ́ ṣe ẹlẹ́yà,tí nwọ́n sì sẹ́ ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìfihàn, tí nwọ́n sì npaniyan, tí nwọ́n sì nṣe ìkógun, irọ́ pípa, olè jíjà, tí nwọ́n sì nṣe àgbèrè, tí nwọ́n sì nru sókè nínú asọ̀ nlá, tí nwọ́n sì nsá jáde bọ́ sínú ilẹ̀ Nífáì, lãrín àwọn ará Lámánì— Àti nítorí ìwà búburú nwọn nlá yĩ, àti lílérí nínú agbára nwọn, a sì fi nwọ́n sílẹ̀ nínú agbára nwọn; nítorínã ni nwọn kò ṣe ní ìlọsíwájú, ṣùgbọ́n tí a nfìyàjẹ nwọn, tí a sì lù nwọ́n, tí àwọn ará Lámánì sì lé nwọn, títí nwọ́n fi pàdánù púpọ̀ nínú gbogbo ilẹ̀ nwọn. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Móróníhà wãsù nípa ohun púpọ̀ fún àwọn ènìyàn nã nítorí àìṣedẽdé nwọn, àti Nífáì àti Léhì pẹ̀lú, tí nwọn í ṣe ọmọ Hẹ́lámánì, sì wãsù ohun púpọ̀ sí àwọn ènìyàn nã, bẹ̃ni nwọ́n sì sọtẹ́lẹ̀ nípa ohun púpọ̀ sí nwọn nípa àìṣedẽdé nwọn, àti ohun tí yíò dé bá nwọn bí nwọn kò bá ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn. Ó sì ṣe tí nwọ́n sì ronúpìwàdà, níwọ̀n ìgbàtí nwọ́n ronúpìwàdà nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ní ìlọsíwájú. Nigbàtí Móróníhà ríi pé nwọ́n ronúpìwàdà ó sì nṣíwájú nwọn ní lílọ láti ibì kan dé èkejì, àti láti ìlú-nlá dé ìlú-nlá, àní títí nwọ́n fi gba ìdajì ohun ìní nwọn padà àti ìdajì àwọn ilẹ̀ nwọn gbogbo. Báyĩ sì ni ọdún kọkànlélọ́gọ́ta parí nínú ìjọba àwọn onídàjọ́. Ó sì ṣe ní ọdún kejìlélọ́gọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí Móróníhà kò lè gba ohun ìní àwọn ará Lámánì mọ́. Nítorínã nwọ́n pa èrò nwọn láti gba àwọn ilẹ̀ wọn tí ó kù tì, nítorípé àwọn ará Lámánì pọ̀ tóbẹ̃ tí ó fi ṣòro fún àwọn ará Nífáì láti ni agbara síi lórí nwọn; nítorínã ni Móróníhà ṣe lo gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ láti dãbò bò àwọn ibi tí ó ti gbà. Ó sì ṣe, nítorí bí àwọn ará Lámánì ti pọ̀ tó, àwọn ará Nífáì wà ní ìbẹ̀rù nlá, kí nwọn ó má bã borí nwọn, ki nwọn si tẹ̀ nwọ́n mọ́lẹ̀, kí nwọn ó pa nwọ́n, kí nwọn ó sì pa nwọ́n run. Bẹ̃ni, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí rántí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Álmà, àti àwọn ọ̀rọ̀ Mósíàh; nwọ́n sì ríi pé àwọn ti jẹ́ ọlọ́runlíle ènìyàn, àti tí nwọn kò sì ka òfin Ọlọ́run sí; Àti pé nwọ́n ti yí òfin Mòsíà padà nwọn sì ti tẹ̃ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ nwọn, tàbí èyítí Olúwa ti paláṣẹ kí ó fún àwọn ènìyàn nã; nwọ́n sì ríi pé àwọn òfin nwọ́n ti díbàjẹ́, nwọ́n sì ti di ènìyàn búburú, tóbẹ̃ tí nwọn nṣe búburú àní gẹ́gẹ́bí àwọn ará Lámánì. Àti nítorí àìṣedẽdé nwọn ìjọ nã ti bẹ̀rẹ̀sí rẹ̀hìn; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe aláìgbàgbọ́ nínú ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti nínú ẹ̀mí ìfihàn; ìdájọ́ Ọlọ́run sì súnmọ́ itòsí fún nwọn. Nwọ́n sì ríi pé nwọn kò lágbára mọ́, bí àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì, àti pé Ẹ̀mí Olúwa kò sì dãbò bò nwọ́n mọ́; bẹ̃ni, ó ti kúrò lọ́dọ̀ nwọn nítorí pé Ẹ̀mí Olúwa kò lè gbé nínú àwọn tẹ́mpìlì àìmọ́— Nítorínã ni Olúwa ṣe dáwọ́dúró láti má pa nwọ́n mọ́ nípa ìyanu agbára rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́, nítorípé nwọ́n ti ṣubú sínú ipò àìgbàgbọ́ àti ìwà tí ó burú jùlọ; nwọ́n sì ríi pé àwọn ará Lámánìpọ̀ jù nwọ́n lọ lọ́pọ̀lọpọ̀, àti pé àfi bí nwọn ó bá dìrọ́ mọ́ Olúwa Ọlọ́run nwọn, nwọn yíò ṣègbé ní dandan. Nítorí kíyèsĩ, nwọ́n ríi pé agbára àwọn ará Lámánì pọ̀ tó agbára tiwọn, àní ni ẹnikan sí ẹnikan. Báyĩ sì ni nwọ́n ṣe bọ́ sí ipò ìwà ìrékọjá nlá yĩ; bẹ̃ni, báyĩ ni nwọ́n ṣe di aláìlágbára, nítorí ìwà ìrékọjá nwọn, lãrín ìwọ̀n ọdún tí kò pọ̀. 5 Nífáì àti Léhì lo ara nwọn fún iṣẹ́ ìwãsù—Orúkọ nwọn tọ́ka nwọn sí gbígbé ayé nwọn ní ìbámu pẹ̀lú bí àwọn bàbá nlá nwọn ṣe gbé ayé nwọn—Krístì ṣe ìràpadà fún àwọn tí ó ronúpìwàdà—Nífáì àti Léhì yí ọkàn ènìyàn púpọ̀ padà a sì jù nwọ́n sínú tũbú, iná sì yí nwọn ká—Ìkũku tí ó ṣókùnkùn sì bò àwọn ọgọ̣́rún mẹ́ta ènìyàn—Ayé mì tìtì, ohùn kan sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn láti ronúpìwàdà—Nífáì àti Léhì bá àwọn ángẹ́lì sọ̀rọ̀, iná sì yí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã ká. Ní ìwọ̀n ọdún 30 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe nínú ọdún yĩ kannã, kíyèsĩ, Nífáì fi ìtẹ́ ìdájọ́ nã sílẹ̀ fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ Sẹ́sórámù. Nítorítí gẹ́gẹ́bí ó ṣe wà pé nípa ohùn àwọn ènìyàn ni a ṣe fi àwọn òfin nwọn àti àwọn ìjọba nwọn lélẹ̀, àti pé àwọn tí ó yan búburú pọ̀ ju àwọn tí ó yan rere, nítorínã nwọ́n nmúrasílẹ̀ de ìparun ara nwọn, nítorítí àwọn òfin ti díbàjẹ́. Bẹ̃ni, èyí nìkan sì kọ́; nwọ́n jẹ́ ọlọ́rùnlíle ènìyàn, tóbẹ̃ tí kò ṣeéṣe láti ṣe àkóso lórí nwọn pẹ̀lú òfin tabi àìṣègbè, láìjẹ́ fún ìparun nwọn. Ó sì ṣe tí Nífáì kãrẹ nítorí àìṣedẽdé nwọn; ó sì fi ìtẹ́ ìdájọ́ sílẹ̀, ó si fi ara rẹ̀ fún wíwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní gbogbo ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀, àti arákùnrin rẹ̀ Léhì pẹ̀lú, ní ìyókù gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; Nítorítí nwọ́n rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí bàbá nwọn Hẹ́lámánì bá nwọn sọ. Èyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá nwọn sọ: Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ọmọ mi, mo fẹ́ kí ẹ̀yin ó rántí láti pa òfin Ọlọ́run mọ́; èmi sì fẹ́ kí ẹ̀yin ó kéde àwọn ọ̀rọ̀ yĩ fún àwọn ènìyàn. Ẹ̀ kíyèsĩ, èmi ti fún nyín ní orúkọ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ tí nwọn jáde wa láti ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù; mo sì ṣe èléyĩ pé nígbàtí ẹ̀yin ó bá rántí orúkọ nyín pé ẹ̀yin ó lè rántí nwọn; tí ẹ̀yin bá sì rántí nwọn ẹ̀yin yiò rántí àwọn iṣẹ́ nwọn; nígbàtí ẹ̀yin bá sì rántí àwọn iṣẹ́ nwọn ẹ̀yin yíò mọ̀ pé a ti sọọ́, a sì ti kọọ́, pé nwọ́n dára. Nítorínã, ẹ̀yin ọmọ mi, mo fẹ́ kí ẹ̀yin ó ṣe èyítí ó dára, kí a lè sọ nípa nyín, àti kí a kọọ́, àní gẹ́gẹ́bí a ti sọọ́ àti bí a sì ti kọọ́ nípa nwọn. Àti nísisìyí ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ kíyèsĩ mo ní ohun kan tí èmi tún fẹ́ kí ẹ̀yin ó ṣe, ohun nã sì ni, pé kí ẹ̀yin ó máṣe ṣe àwọn ohun wọ̀nyí láti gbéraga, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin ó ṣe àwọn ohun wọ̀nyí láti lè to ìṣura jọ fún ara nyín ní ọ̀run, bẹ̃ni, èyítí ó wà láéláé, àti èyítí kò lè parẹ́; bẹ̃ni, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹ̀bùn iyebíye nnì tí í ṣe ìyè àìnípẹ̀kun, èyítí àwa mọ̀ dájú wipé a ti fifún àwọn bàbá nlá wa. A!, rántí, ẹ rántí, ẹ̀yin ọmọ mi, àwọn ọ̀rọ̀ èyítí ọba Bẹ́njámínì sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀; bẹ̃ni, ẹ rántí pé kò sí ọ̀nà míràn tàbí ipa ọ̀nà èyítí a fi lè gba ènìyàn là, àfi nípa ìṣètùtù ẹ̀jẹ̀ Jésù Krístì, tí nbọ̀wá; bẹ̃ni, kí ẹ rántí pé ó nbọ̀wá láti ra aráyé padà. Ẹ sì tún rántí àwọn ọ̀rọ̀ ti Ámúlẹ́kì sọ fún Sísrọ́mù, nínú ìlú-nlá Amonáíhà; nítorítí ó wí fún un pé Olúwa nbọ̀ dájúdájú láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, ṣùgbọ́n kò lè wá láti rà nwọ́n padà nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, ṣùgbọ́n láti rà nwọ́n padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn. À sì ti fi agbára fún un láti ọ̀dọ̀ Bàbá láti rà nwọ́n padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn nítorí ìrònúpìwàdà; nítorínã ni ó ṣe rán àwọn ángẹ́lì rẹ̀ láti kéde ìròhìn ayọ̀ nípa ti ìrònúpìwàdà, èyítí í mú ènìyàn wá sínú agbára Olùràpadà nã, sí ti ìgbàlà ọkàn nwọn. Àti nísisìyí, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ rántí, ẹ rántí pé lórí àpáta Olùràpadà wa, ẹnití íṣe Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ni ẹ̀yin níláti kọ́ ìpìlẹ̀ nyín lé, pé nígbàtí èṣù bá sì fẹ́ ẹ̀fũfù líle rẹ̀ wá, bẹ̃ni, ọ̀pá rẹ̀ nínú ìjì, bẹ̃ni, nígbàtí gbogbo àwọn òkúta yìnyín rẹ̀ àti ìjì líle rẹ̀ bá rọ̀ lé yín kò lè ní agbára lórí yín láti fà yín sínú ọ̀gbun òṣì àti ègbé aláìlópin, nítorí àpáta èyítí a kọ́ yín lé lórí, èyítí íṣe ìpìlẹ̀ tí o dájú, ìpìlẹ̀ èyítí ènìyàn kò lè ṣubú lórí rẹ̀ bí nwọ́n bá kọ́ lé e lórí. Ó sì ṣe tí èyí sì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Hẹ́lámánì fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀; bẹ̃ni, ó kọ́ nwọn ní ohun púpọ̀ tí a kò kọ sílẹ̀, àti àwọn ohun púpọ̀ tí a kọ sílẹ̀. Nwọ́n sì rántí ọ̀rọ̀ rẹ̀; nítorínã nwọ́n sì jáde lọ, ní pípa òfin Ọlọ́run mọ́, láti kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lãrín gbogbo àwọn ènìyàn Nífáì, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀; Àti láti ibẹ̀ lọ sí ìlú-nlá Gídì; àti láti ìlú-nlá Gídì lọ sí ìlú-nlá Múlẹ́kì; Àní nwọ́n sì lọ láti ìlú-nlá kan dé òmíràn, títí nwọn fi lọ lãrín gbogbo àwọn ènìyàn Nífáì tí nwọn wà ní ilẹ̀ tí ó wà lápá gũsù; àti láti ibẹ̀ lọ sí inú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, lãrín àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí nwọ́n wãsù pẹ̀lú agbára nlá, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi da púpọ̀ nínú àwọn olùyapa kúrò nnì lãmú, àwọn tí nwọ́n ti jáde lọ kúrò lára àwọn ará Nífáì ṣãjú, tóbẹ̃ tí nwọn jáde wá tí nwọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nwọn tí a sì rì nwọn bọmi sí ìrònúpìwàdà, nwọ́n sì padà ní ojúkannã lọ bá àwọn ará Nífáì láti gbìyànjú láti ṣe àtúnṣe fún nwọn ní ti àwọn ohun búburú tí nwọ́n ti ṣe. Ó sì ṣe tí Nífáì àti Léhì wãsù sí àwọn ará Lámánì pẹ̀lú agbára àti àṣẹ nlá, nítorípé a ti fún nwọn ní agbára àti àṣẹ láti lè sọ̀rọ̀, a sì ti fún nwọn ní ohun tí nwọn yíò sọ— Nítorínã nwọ́n sì sọ̀rọ̀ sí ìyàlẹ́nu nlá àwọn ará Lámánì, sí ti ìdánilójú fún nwọn, tóbẹ̃ tí àwọn tí a rìbọmi sí ìrònúpìwàdà nínú àwọn ará Lámánì nã tí ó wà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà jẹ́ ẹgbãrin, tí nwọ́n sì ní ìdánilójú nípa àṣà búburú àwọn bàbá nwọn. Ó sì ṣe tí Nífáì àti Léhì kúrò níbẹ̀ láti lọ sínú ilẹ̀ Nífáì. Ó sì ṣe tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì kan mú nwọn tí nwọ́n sì jù nwọ́n sínú tũbú; bẹ̃ni, àní nínú tũbú kannã nínú èyítí àwọn ìránṣẹ́ Límháì ju Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sí. Lẹ́hìn tí a sì ti jù nwọ́n sínú tũbú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ láì fún nwọn ní óúnjẹ, ẹ kíyèsĩ, nwọ́n jáde lọ sínú tũbú nã láti mú nwọn kí nwọ́n sì pa nwọ́n. Ó sì ṣe tí ohun nã èyítí ó rí bí iná yí Nífáì àti Léhì ká, àní tóbẹ̃ tí nwọn kò lè fọwọ́kàn nwọ́n rárá ní ìbẹ̀rù pé àwọn yíò jóná. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Nífáì àti Léhì kò jóná; nwọ́n sì wà bí ẹnití ó wà nínú iná tí nwọn kò sì jóná. Nígbàtí nwọ́n sì ríi pé ọ̀wọ́ iná ni ó yí nwọn ká, àti pé kò jó nwọn, ọkàn nwọn gba ìkìyà. Nítorítí nwọ́n ríi pé àwọn ará Lámánì kò lè fọwọ́kàn nwọ́n rárá; bẹ̃ni nwọn kò lè súnmọ́ nwọn, ṣùgbọ́n nwọ́n dúró bí èyítí ó yadi pẹ̀lú ìyàlẹ́nu. Ó sì ṣe tí Nífáì àti Léhì dide dúró tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sọ̀rọ̀ sí nwọn, wípé: Ẹ má bẹ̀rù, nítorí ẹ kíyèsĩ, Ọlọ́run ni ẹnití ó fi ohun ìyanu yĩ hàn yín, nínú èyítí a fi hàn nyín pé ẹ̀yin kò lè fi ọwọ́ nyín kàn wá láti pa wá. Ẹ sì kíyèsĩ, nígbàtí nwọ́n sọ àwọn ọ̀rọ̀ yĩ tán, ilẹ̀ mì tìtì púpọ̀púpọ̀, àwọn ògiri inú tũbú nã sì mì tìtì bí èyítí nwọn yíò wó lulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, nwọn kò ṣùbú lulẹ̀. Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Nífáì tí ó ti yapa ni àwọn tí ó wà nínú tũbú nã. Ó sì ṣe tí ikũku tí ó ṣókùnkùn bò nwọn mọ́lẹ̀, ẹ̀rù nlá sì balé nwọn. Ó sì ṣe tí ohùn kan sì wá bí èyítí ó wá láti òkè ikũku tí ó ṣókùnkùn nã, tí ó wípé: Ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà, ẹ sì ṣíwọ́ pípa àwọn ìránṣẹ́ mi tí a rán sí nyín láti mú ìhìn-rere wá fún nyín. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí nwọ́n gbọ́ ohùn yĩ, tí nwọ́n sì rí i pé kì í ṣe ohùn ãrá, bẹ̃ni tí kì í ṣe ohùn ìrúkèrúdò nlá, ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ohùn pẹ̀lẹ́ dídákẹ́ rọ́rọ́ ni, bí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, tí ó sì wọ inú ọkàn lọ— Àti l’áìṣírò ohùn nã jẹ́ èyítí ó wà ní pẹ̀lẹ́ dídákẹ́ rọ́rọ́, ẹ kíyèsĩ ilẹ̀ mì tìtì púpọ̀púpọ̀, àwọn ògiri inú tũbú sì tún gbọ̀n rìrì, bí èyítí yíò wó lulẹ̀; ẹ sì kíyèsĩ ikũku tí ó ṣókùnkùn nã, èyítí ó ti bò nwọ́n mọ́lẹ̀, kò túká— Ẹ sì kíyèsĩ ohùn nã tún wá, ó wípé: Ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà, nítorítí ìjọba ọ̀run fẹ́rẹ̀ dé; ẹ sì ṣíwọ́ pípa àwọn ìránṣẹ́ mi. Ó sì ṣe tí ilẹ̀ tún mì tìtì, tí àwọn ògiri sì gbọ̀n rìrì. Àti pẹ̀lú ni ohùn nã tún wá lẹ̃kẹ̀ta, tí ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìyanu fún nwọn èyítí ẹnìkẹ́ni kò lè sọ; àwọn ògiri nã sì tún gbọ̀n rìrì, ilẹ̀ sì mì tìtì bí ẹnipé yíò pínyà. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì kò lè sá nítorí ìkukù tí ó ṣókùnkùn nã èyítí ó bò nwọ́n mọ́lẹ̀; bẹ̃ni, àti pé nwọn kò lè kúrò lójúkan nítorí ẹ̀rù tí ó bà nwọ́n. Nísisìyí ẹnìkan wà lãrín nwọn tí í ṣe ará Nífáì nípa ìbí, ẹnití ó wà nínú ìjọ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ rí ṣùgbọ́n tí ó ti yapa kúrò lára nwọn. Ó sì ṣe tí ó yísẹ̀ padà, sì kíyèsĩ, ó rí ojú Nífáì àti Léhì nínú ikũku tí ó sokunkun nã; ẹsì kíyèsĩ, nwọ́n ndán yinrinyinrin, àní bí ojú àwọn ángẹ́lì. Ó sì ríi pé nwọ́n gbé ojú nwọn sókè sí ọ̀run; nwọ́n sì wà bí ẹnití nsọ̀rọ̀ tàbí tí ó ngbé ohùn rẹ̀ sókè sí ẹnìkan èyítí nwọ́n nwò. Ó sì ṣe tí ọkùnrin nã sì ké lóhùnrara sí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, kí nwọn ó lè yípadà kí nwọn ó sì wò. Sì kíyèsĩ a fún nwọn ní agbára kí nwọ́n lè yípadà kí nwọ́n sì wò; nwọ́n sì rí ojú Nífáì àti Léhì. Nwọ́n sì wí fún ọkùnrin nã pé: Kíyèsĩ, kíni ìtumọ̀ àwọn ohun wọ̀nyí, àti pé tani ẹni nã tí àwọn ọkùnrin yĩ nbá sọ̀rọ̀? Nísisìyí orúkọ ọkùnrin nã ni Ámínádábù. Ámínádábù sì wí fún nwọn pé: Àwọn ángẹ́lì Ọlọ́run ni nwọ́n nbá sọ̀rọ̀. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì wí fún un pé: Kíni àwa yíò ṣe, tí ìkũkù tí ó ṣókùnkùn yĩ yíò ká kúrò kí ó má sì bò wá mọ́lẹ̀? Ámínádábù sì wí fún nwọn pé: Ẹ níláti ronúpìwàdà kí ẹ sì kígbe pé ohùn nã, àní títí ẹ̀yin ó fi ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì, ẹnití Álmà, àti Ámúlẹ́kì, àti Sísrọ́mù ti kọ́ nyín lẹ́kọ̣́ nípa rẹ̀; àti nígbàtí ẹ̀yin o bá ṣe eleyĩ, a ó ka ìkũkù tí ó ṣókùnkùn nnì kúrò kí ó má lè bò nyín mọ́lẹ̀ mọ́. Ó sì ṣe tí gbogbo nwọn bẹ̀rẹ̀sí kígbe pé ohùn ẹni nã tí ó ti mí ilẹ̀ tìtì; bẹ̃ni, nwọ́n sì nkígbe àní títí ìkũkù tí ó ṣókùnkùn nã fi túká. Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n wò yíká, tí nwọ́n sì ríi pé ìkũkù tí ó ṣókùnkùn nã tí tuka láti má bò nwọ́n mọ́lẹ̀, ẹ kíyèsĩ, nwọ́n ríi pé ọ̀wọ́ iná yi nwọn ka, bẹ̃ni ọkàn kọ̣́kan, pẹ̀lú ọwọ iná. Nífáì àti Léhì sì wà lãrín nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n wà ní àkámọ́; bẹ̃ni, nwọ́n wà bí ẹnití ó wà lãrín iná tí njó, síbẹ̀ kò sì pa nwọ́n lára, bẹ̃ni kò sì ràn mọ́ àwọn ògiri inú tũbú; nwọ́n sì kún fún ayọ̀ nnì èyítí ẹnu kò lè sọ àti tí ó kún fún ògo. Ẹ sì kíyèsĩ, Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run sì sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀run, ó sì wọ inú ọkàn nwọn lọ, ó sì kún inú nwọn bí iná, nwọ́n sì lè sọ ọ̀rọ̀ ìyanu jáde. Ó sì ṣe tí ohùn kan jáde tọ̀ nwọ́n wá, bẹ̃ni, ohùn dáradára kan, èyítí ó dàbí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, tí ó wípé: Àlãfíà, àlãfíà fún nyín, nítorí ìgbàgbọ́ tí ẹ̀yin ní nínú Àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹnití ó ti wà láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Àti nísisìyí, nígbàtí nwọ́n gbọ́ èyĩ nwọ́n gbé ojú nwọn sókè bí láti lè wo ibití ohùn nã gbé wá; ẹ sì kíyèsĩ, nwọ́n rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀; tí àwọn ángẹ́lì sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run jáde wá tí nwọn sì njíṣẹ́ fún nwọn. Ó sì tó bí ènìyàn ọgọrun mẹ́ta tí nwọn rí ti nwọn si gbọ́ ohun wọ̀nyí, a sì ní kí nwọn jáde lọ kí nwọn ó má sì bẹ̀rù, bẹ̃ni kí nwọn ó má ṣe ṣiyèméjì. Ó sì ṣe tí nwọ́n jáde lọ, tí nwọ́n sì njíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn nã, tí nwọn nsọ gbogbo ohun tí nwọ́n ti gbọ́ àti èyítí nwọ́n ti rí jákè-jádò ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì nã gba ìdánilójú nípa nwọn, nítorí títóbi ẹ̀rí tí nwọ́n ti gbà. Àti pé gbogbo àwọn tí nwọ́n ti gba ìdánilójú ni ó kó àwọn ohun ìjà nwọn lélẹ̀, àti àwọnikorira tí nwọ́n ní àti àṣà àwọn bàbá nwọn pẹ̀lú. Ó sì ṣe tí nwọ́n jọ̀wọ́ àwọn ilẹ̀ tí í ṣe ìní àwọn ará Nífáì sílẹ̀ fún nwọn. 6 Àwọn ará Lámánì olódodo wãsù sí àwọn ará Nífáì oníwà búburú—Àwọn ará méjẽjì ní ìlọsíwájú ní àsìkò tí àlãfíà àti ọ̀pọ̀ wa—Lúsíférì, ẹnití í ṣe olùpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ru ọkàn àwọn ènìyàn búburú àti àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì sókè sí ìpànìyàn ati ìwàbúburú—Àwọn ọlọ́ṣà nã gba ìjọba àwọn ará Nífáì. Ní ìwọ̀n ọdún 29 sí 23 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe nígbàtí ọdún kejìlélọ́gọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ ti parí, gbogbo nkan wọ̀nyí sì ti rékọjá tí èyítí ó pọ̀ jù nínú àwọn ará Lámánì sì ti di olódodo ènìyàn, tóbẹ̃ tí ìwà ododo nwọn tayọ ti àwọn ará Nífáì, nítorí ìwà ìtẹramọ́ nwọn àti àìyísẹ̀padà kúrò nínú ìgbàgbọ́ nã. Nítorí kíyèsĩ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ará Nífáì nã ní ó ti sé àyà nwọn le tí nwọ́n kò sì ronúpìwàdà, àti nínú ìwà búburú, tóbẹ̃ tí nwọ́n kọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti gbogbo ìwãsù àti ìsọtẹ́lẹ̀ èyítí ó wa pẹ̀lú nwọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ènìyàn ìjọ nã ní ayọ̀ nlá nítorí ìyílọ́kànpadà àwọn ará Lámánì, bẹ̃ni, nítorí ìjọ Ọlọ́run, èyítí a ti fi lélẹ̀ lãrín nwọn. Nwọ́n sì ní ìdàpọ̀ ní ọkàn sí ẹlòmíràn, nwọ́n sì nbá ara nwọn yọ̀ ní ọkàn sí ẹlòmíràn, nwọ́n sì ní ayọ̀ nla. Ó sì ṣe tí púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì nã sì sọ̀kalẹ̀ wá sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí nwọn sì sọ nípa bí ìyílọ́kànpadà nwọ́n ti rí fún àwọn ará Nífáì, nwọ́n sì gbà nwọ́n níyànjú láti ní ìgbàgbọ́ àti ìrònúpìwàdà. Bẹ̃ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ó sì wãsù pẹ̀lú agbára nlá àti àṣẹ, tí nwọ́n sì mú púpọ̀ nínú nwọn bọ́sí ipò ìrẹraẹnisílẹ̀, láti lè di onírẹ̀lẹ̀ ọmọ ẹ̀hìn Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́-àgùtàn nã. Ó sì ṣe tí púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì nã lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá; tí Nífáì àti Léhì sì lọ pẹ̀lú sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá; láti wãsù sí àwọn ènìyàn nã. Báyĩ sì ni ọdún kẹtàlélọ́gọ́ta parí. Ẹ sì kíyèsĩ, àlãfíà wà ní gbogbo ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí àwọn ará Nífáì nlọ sí èyíkeyí apá ilẹ̀ nã tí ó bá wù nwọ́n, bóyá lãrín àwọn ará Nífáì tàbí àwọn ará Lámánì. Ó sí ṣe tí àwọn ará Lámánì nã lọ sí ibikíbi tí ó bá wù nwọ́n, bóyá lãrín àwọn ará Lámánì tàbí lãrín àwọn ará Nífáì; báyĩ ni nwọ́n sì ṣe ní ìbáṣepọ̀ dáradára ní ọkàn sí òmíràn, láti rà àti láti tà, àti láti jèrè, gẹ́gẹ́bí ó ti wù nwọ́n. Ó sì ṣe tí nwọ́n sì di ọlọ́rọ̀ènìyàn púpọ̀púpọ̀, àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Nífáì; nwọ́n sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti fàdákà, àti onírurú òkúta olówóiyebíye, ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù àti ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá. Nísisìyí ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù ni nwọ́n npè ní Léhì, àti ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá ni nwọ́n npè ní Múlẹ́kì, èyítí nwọ́n pè bẹ̃ lẹ́hìn orúkọ ọmọ Sẹdẹkíàh; nítorítí Olúwa ni ó mú Múlẹ́kì wá sínú ilẹ̀ apá àríwá, àti Léhì sínú ilẹ̀ apá gũsù. Ẹ sì kíyèsĩ, onírurú wúrà ni ó wà nínú àwọn ilẹ̀ yĩ, àti fàdákà, àti irin àìpò olówó iyebíye lóríṣiríṣi; àwọn oníṣẹ́ ọnà sì wa pẹ̀lú, àwọn ẹnití nfi irin àìpò ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́, tí nwọ́n sì nyọ́ọ; báyĩ nwọ́n sì di ọlọ́rọ̀. Nwọ́n sì gbin ọkà lọ́pọ̀lọpọ̀, ní apá àríwá àti ní apá gúsù; nwọ́n sì gbilẹ̀ púpọ̀púpọ̀, ní apá àríwá àti ní gúsù. Nwọ́n sì pọ̀ síi nwọ́n sì di alágbára ní ilẹ̀ nã. Nwọ́n sì nsin ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbo, àti ọ̀wọ́ ẹran, bẹ̃ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àbọ́pa. Ẹ kíyèsĩ àwọn obìnrin nwọn sì nsiṣẹ́, nwọ́n sì nran òwú, nwọ́n sì nṣe onírurú aṣọ, àwọn aṣọ olówó iyebíye àti àwọn onírurú aṣọ láti bò nwọ́n lára. Báyĩ sì ni ọdún kẹrìnlélọ́gọ́ta kọjá lọ lalãfia. Ní ọdún karundinlãdọrin nwọn sì ní ayọ̀ àti àlãfíà tí ó pọ̀, bẹ̃ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwãsù àti ìsọtẹ́lẹ̀ púpọ̀púpọ̀ nípa ohun tí yíò di mímúṣẹ. Báyĩ sì ni ọdún karundinlãdọrin kọjá lọ. Ó sì ṣe ní ọdún kẹrìndínlãdọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, ẹ kíyèsĩ, ẹni-àìmọ̀ kan sì pa Sẹ́sórámù bí ó ṣe wà lórí ìtẹ́ ìdájọ́. Ó sì ṣe nínú ọdún kan nã, tí nwọn pa ọmọ rẹ̀ ọkùnrin nã ẹnití àwọn ènìyàn ti yàn rọ́pò rẹ. Báyĩ sì ni ọdún kẹrìndínlãdọ́rin dópin. Nínú ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹtàdínlãdọ́rin ni àwọn ènìyàn nã sì tún bẹ̀rẹ̀sí hu ìwà búburú èyítí ó pọ̀ púpọ̀. Nítorí kíyèsĩ, Olúwa ti bùkúnfún nwọn fún ìgbà pípẹ́ pẹ̀lú àwọn ọrọ̀ ayé tóbẹ̃ tí kò sí ẹnití ó ru nwọn sókè sí ìbínú, tàbí sí ogun, tàbí sí ìtàjẹ̀sílẹ̀; nítorínã nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí gbé ọkàn nwọn lé ọrọ̀ nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí lépa láti lè ga ju ara nwọn lọ; nítorínã nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìpànìyàn ní ìkọ̀kọ̀, àti láti jalè àti láti ṣe ìkógun, láti lè rí ìfà. Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwọn apànìyàn àti àwọn olè nnì jẹ́ àwọn ẹgbẹ́ tí Kíṣkúmẹ́nì àti Gádíátónì kójọ. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí nwọ́n ti pọ̀, àní lãrín àwọn ará Nífáì, ní ẹgbẹ́ ti Gádíátónì. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, nwọ́n pọ̀ lãrín àwọn ará Lámánì nínú àwọn tí ó burú jù lọ. A sì pè nwọn ní àwọn ọlọ́sà àti apànìyàn Gádíátónì. Àwọn sì ni ó pa olórí àlùfã Sẹ́sórámù, àti ọmọ rẹ̀, nígbàtí ó joko lórí ìtẹ́ ìdájọ́; ẹ sì kíyèsĩ, a kò rí nwọn. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé àwọn olóṣà wà lãrín nwọn, nwọn sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi; nwọ́n sì lo gbogbo agbára tí nwọ́n ní láti pa nwọ́n run lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Sátánì sì ru ọkàn èyítí ó pọ̀ jù nínú àwọn ará Nífáì sókè, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi darapọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà nã, nwọ́n sì bá nwọn mulẹ̀ nínú ìmùlẹ̀ àti ìbúra nwọn, pé nwọn yíò dábò bò; wọn yíò sì pa ara wọn mọ́ nínú ìṣòro-kíṣòro èyíówù kí nwọ́n ó lè wà, láti má lè jìyà fún ìwà-ìpànìyàn nwọn, àti ìkógun nwọn, àti olè jíjà nwọn. Ó sì ṣe tí nwọ́n ní àwọn àmì nwọn, bẹ̃ni, àwọn àmì ìkọ̀kọ̀ nwọn, àti àwọn ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ nwọn; èyí sì rí bẹ̃ kí nwọn ó lè dá arákùnrin nwọn tí ó bá ti wọ inú ìmùlẹ̀ nã mọ, pé ìwà búburú yìówù kí arákùnrin rẹ̀ ó huarákùnrin rẹ̀ míràn kò ni pãlára, tàbí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yìókù, tí nwọ́n ti bá nwọn mulẹ̀. Báyĩ sì ni nwọ́n lè pànìyàn, tàbí ṣe ìkógun, tàbí jalè, kí nwọn ó sì ṣe àgbèrè, àti onírurú ìwà búburú, ní ìlòdì sí òfin orílẹ̀-èdè nwọn àti òfin Ọlọ́run nwọn pẹ̀lú. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ẹgbẹ́ nwọn tí ó sì jẹ́ kí ìwà búburú àti ìwà ìríra nwọn ó di mímọ̀ sí aráyé, ni nwọn ó pè lẹ́jọ́, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú òfin orílẹ̀ èdè wọn, ní ìbámu pẹ̀lú òfin búburú nwọn, èyítí Gádíátónì àti Kíṣkúmẹ́nì fi fún nwọn. Nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ìbúra àti ìmùlẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wọ̀nyí ni Álmà paláṣẹ fun ọmọ rẹ pé kò gbọdọ̀ kọjá lọ sínú ayé, ní ìbẹ̀rù pé nwọn yíò jẹ́ ọ̀nà ìparun fún àwọn ènìyàn nã. Nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ìbúra àti ìmùlẹ̀ ìkọ̀kọ̀ nnì kò tẹ Gádíátónì lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn àkosílẹ̀ tí a fi lé Hẹ́lámánì lọ́wọ́; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, a fi nwọ́n sínú ọkan Gádíátónì nípasẹ̀ ẹ̀dá nã tí ó tan àwọn òbí wa àkọ́kọ́ láti jẹ nínú èso nnì tí a kà lẽwọ̀— Bẹ̃ni, ẹ̀dá kan nã tí ó dìtẹ̀ pẹ̀lú Káìnì, pé bí ó bá pa Ábẹ́lì arákùnrin rẹ̀ aráyé kò lè mọ̀ nípa rẹ̀. Ó sì dìtẹ̀ pẹ̀lú Káínì àti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ láti ìgbà nã lọ. Àti pẹ̀lú pé ẹ̀dá ọ̀hún kannã ni ó fi sínú àwọn ènìyàn nã láti kọ́ ilé-ìṣọ́ gíga láti lè lọ sí ọ̀run. Àti pé ẹ̀dá ọ̀hún kannã ni ó darí àwọn ènìyàn nã tí nwọn kúrò láti ilé-ìṣọ́ nã wá sínú ilẹ́ yĩ; tí nwọn tan iṣẹ́ òkùnkùn àti ohun ẽrí kalẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, títí ó fi já àwọn ènìyàn nã lulẹ̀ sí ipò ìparun pátápátá, àti sínú ọ̀run àpãdì ayérayé. Bẹ̃ni, ẹ̀dá ọ̀hún kannã ni ó fi sínú ọkàn Gádíátónì pé kí ó tẹramọ́ iṣẹ́ òkùnkùn ní ṣíṣe, àti ti ìpànìyàn ní ìkọ̀kọ̀; ó sì ti nṣe báyĩ láti ìbẹ̀rẹ̀ ọmọ ènìyàn àní títí dé àkokò yĩ. Sì kíyèsĩ, òun ni ẹnití í ṣe olùpilẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀. Sì kíyèsĩ, ó túbọ̀ tẹramọ́ iṣẹ́ òkùnkùn àti ìpànìyàn ní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀, ó sì nfi àwọn ìmọ̀ búburú nwọn, àti àwọn ìbúra nwọn, àti àwọn ìmùlẹ̀ nwọn, àti àwọn ìmọ̀ ìwà búburú nwọn tí ó tóbi, láti ìran dé ìran gẹ́gẹ́bí ó ṣe lè wọnú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn tó. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ó ti wọnú ọkàn àwọn ará Nífáì lọ; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí nwọ́n di ènìyàn tí ó burú púpọ̀púpọ̀; bẹ̃ni, èyítí ó pọ̀ jù nínú nwọn ni ó ti yísẹ̀padà kúrò nínú ọ̀nà òdodo, tí nwọ́n sì ntẹ òfin Ọlọ́run mọ́lẹ̀, tí nwọ́n sì yípadà sí ọ̀nà ara nwọn, tí nwọ́n sì ya ère fún ara nwọn pẹ̀lú àwọn wúrà àti àwọn fàdákà nwọn. Ó sì ṣe tí gbogbo àwọn àìṣedẽdé yĩ dé bá nwọn lãrín ìwọ̀n ọdún díẹ̀, tóbẹ̃ tí púpọ̀ rẹ̀ ni ó dé bá nwọn nínú ọdún kẹtàdínlãdọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì. Nwọ́n sì ndàgbà nínú àwọn àìṣedẽdé nwọn nínú ọdún kejìdínlãdọ́rin pẹ̀lú, sí ìbànújẹ́ àti ipohunrere-ẹkun àwọn olódodo. Àwa sì ríi báyĩ pé àwọn ará Nífáì bẹ̀rẹ̀sí jó àjorẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́, nwọ́n sì ndàgbà nínú ìwà búburú àti ìwà ẽrí, tí àwọn ará Lámánì sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà púpọ̀ nínú ìmọ̀ Ọlọ́run nwọn; bẹ̃ni,nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa àwọn ìlànà àti òfin mọ́, àti láti máa rìn nínú òtítọ́ àti ìdúróṣinṣin níwájú rẹ̀. Báyĩ sì ni a ríi tí Ẹ̀mí Olúwa bẹ̀rẹ̀sí fà sẹ́hìn lọ́dọ̀ àwọn ará Nífáì, nítorí ìwà búburú àti ọkàn líle nwọn. Báyĩ sì ni àwa ríi tí Olúwa bẹ̀rẹ̀sí da Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lé àwọn ará Lámánì lórí, nítorí ìrọ̀rùn àti ìfẹ́-inú nwọn làti gba ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́. Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì dọdẹ àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà Gádíátónì; nwọ́n sì nwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lãrín àwọn tí ó níwà búburú jùlọ nínú nwọn, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi pa àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà yĩ run pátápátá kúrò lãrín àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe ní ìdà kejì, tí àwọn ará Nífáì mú nwọn gbèrú, nwọ́n sì ràn nwọ́n lọ́wọ́, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn tí ó burú jù nínú nwọn, títí nwọ́n fi tàn ká gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Nífáì, tí nwọ́n sì ti kó sínú púpọ̀ nínú àwọn olódodo títí nwọ fi gba ìṣe nwọn gbọ́ tí nwọ́n sì nbá nwọn se àjọpín nínú ìkógun nwọn, àti láti darapọ̀ mọ́ nwọ́n nínú àwọn ìpànìyàn àti ìkójọpọ̀ ní ìkọ̀kọ̀ nwọn. Báyĩ sì ni nwọ́n gba gbogbo àkóso ìjọba nã, tóbẹ̃ tí nwọ́n sì tẹ àwọn tálákà àti àwọn ọlọ́kàn tútù, àti àwọn onírẹ̀lẹ̀ tí nwọn ntẹ̀lé Ọlọ́run mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ nwọn tí nwọ́n sì nlù nwọ́n, tí nwọ́n sì nfìyà jẹ nwọ́n tí nwọ́n sì se àkíyèsí nwọn. Báyĩ àwa sì ríi pé nwọ́n wà ní ipò tí ó burú, tí nwọ́n sì nmúrasílẹ̀ de ìparun ayérayé. Ó sì ṣe tí ọdún kejìdínlãdọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí báyĩ. Ìsọtẹ́lẹ̀Nífáì, ọmọHẹ́lámánì—Ọlọ́run kìlọ̀ fún àwọn ará Nífáì pé òun yíò bẹ̀ nwọ́n wò nínú ìbínú rẹ̀, sí ìparun nwọn pátápátá àfi bí nwọ́n bá ronúpìwàdà kúrò nínú ìwà búburú nwọn. Ọlọ́run fi àjàkálẹ̀ àrùn bá àwọn ènìyàn Nífáì jà; nwọ́n ronúpìwàdà nwọn sì yípadà sọ́dọ̀ rẹ̀. Sámúẹ́lì, tí í ṣe ará Lámánì, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ará Nífáì. Èyítí a kọ sí àwọn orí 7 titi ó fi dé 16 ní àkópọ̀. 7 Nwọn kọ Nífáì ní apá àríwá ó sì padà sí Sarahẹ́múlà—Ó gbàdúrà lórí ilé ìṣọ́ tí ó wà nínú ọgbà rẹ̀ ó sì ké pe àwọn ènìyàn nã pé kí nwọn ó ronúpìwàdà àbí kí nwọ́n ó parun. Ní ìwọ̀n ọdún 23–21 kí a tó bí Olúwa wa. Kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe ní ọdún kọkàndínlãdọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn ará Nífáì, tí Nífáì, ọmọ Hẹ́lámánì padà sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà láti ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá. Nítorítí ó ti jáde lọ sí ãrin àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ apá àríwá, ó sì wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí nwọn, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun púpọ̀ fún nwọn; Nwọ́n sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, tóbẹ̃ tí kò lè dúró lãrín nwọn, ṣùgbọ́n ó tún padà sí ilẹ̀ ibití a ti bĩ. Nígbàtí ó sì rí àwọn ènìyàn nã nínú ipò tí ó burú jùlọ yĩ, àti tí àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì nnì sì wà lórí ìtẹ́-ìdájọ́—tí nwọn sì ti fi ipá gba agbára àti àṣẹ lórí ilẹ̀nã; tí nwọ́n sì pa òfin Ọlọ́run tì, tí nwọn kò sì ṣe èyítí ó tọ́ rárá níwájú rẹ̀; tí nwọn kò sì hùwà àìṣègbè kankan sí àwọn ọmọ ènìyàn; Tí nwọ́n sì ndá àwọn olódodo lẹ́bi nítorí ìwà òdodo nwọn; tí nwọn jẹ́ kí àwọn tí ó ṣẹ̀ àti àwọn oníwà búburú lọ láìjìyà nítorí owó tí nwọ́n ní; ju gbogbo rẹ̀ lọ tí nwọ́n sì fi nwọ́n sí ipò láti ṣe àkóso ìjọba, láti darí àti láti ṣe èyítí ó wù nwọ́n, kí nwọn ó lè rí èrè àti ògo ayé, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí nwọ́n lè máa hùwà àgbèrè ní ìrọ̀rùn, kí nwọn ó sì jalè, àti kí nwọn ó pànìyàn, àti kí nwọn ó ṣe ìfẹ́ inú nwọn gbogbo— Nísisìyí ìwà búburú nlá yĩ ti dé bá àwọn ará Nífáì, lãrín ìwọ̀n ọdún kúkúrú; nígbàtí Nífáì sì ríi, ọkàn rẹ̀ kún fún ìbànújẹ́ nínú àyà rẹ̀; ó sì kígbe nínú ìrora ọkàn rẹ̀ wípé: Èmi ìbá ti gbé ìgbé ayé mi nígbàtí bàbá mi Nífáì kọ́kọ́ jáde kúrò nínú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, tí èmi ìbá ti yọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ilẹ̀ ìlérí nã; nígbànã tí àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ ọlọ́kàn tútù ènìyàn, tí nwọ́n wà ní ìdúróṣinṣin ní pípa òfin Ọlọ́run mọ́, tí nwọ́n sì lọ́ra láti gbà kí a mú nwọn ṣe àìṣedẽdé; nwọ́n sì yára láti tẹtisi ọrọ Olúwa— Bẹ̃ni, bí ọjọ́ ayé mi bá lè wà ní ìgbà nnì, ìgbà nã ni ẹ̀mí mi yíò láyọ̀ nínú ìwà òdodo àwọn arákùnrin mi. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ìpín mi ni ó jẹ́ láti gbé ayé mi ní àkokò yĩ, àti pé ẹ̀mí mi yíò kún fún ìbànújẹ́ nítorí ìwà búburú yĩ tí àwọn arákùnrin mi nhù. Ẹ sì kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe tí í ṣe lórí ilé ìṣọ́ kan, èyítí ó wà nínú ọgbà Nífáì, tí ó wà lẹba ọ̀nà gbọ́rò tí ó lọ sí ọjà nla, tí ó wà nínú ìlú-nlá Sarahẹ́múlà; nítorínã, Nífáì wólẹ̀ nínú ilé ìṣọ́ nã tí ó wà nínú ọgbà rẹ̀, ilè ìṣọ́ nã sì wà lẹba ẹnu ọ̀nà, tí ọ̀nà gbọ́rò nã sì gba ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ó sì ṣe tí àwọn ọkùnrin kan tí nkọjá lọ rí Nífáì bí ó ti ntú ọkàn rẹ jáde sí Ọlọ́run lórí ilé ìṣọ́ nã; nwọ́n sì sáré lọ láti lọ sọ fún àwọn ènìyàn nã nípa ohun tí nwọ́n ti rí, àwọn ènìyàn nã sì péjọ ní ọ̀gọ̣́rọ̀ láti lè mọ́ ohun tí ó fa irú ìkẹdùn tí ó tó èyí fún ìwà búburú àwọn ènìyàn. Àti nísisìyí, nígbàtí Nífáì dìde ó rí àwọn ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn tí nwọ́n ti péjọ. Ó sì ṣe tí ó la ẹnu rẹ̀ tí ó sì wí fún nwọn pe: Ẹ kíyèsĩ, kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin fi péjọ? Kí èmi o ha lè sọ nípa àìṣedẽdé nyín fún nyín bí? Bẹ̃ni, nítorítí èmi gun orí ilé-ìṣọ́ mi lọ láti lè gbàdúrà tọkàn-tọkàn sí Ọlọ́run mi, nitorí ọkàn mi tí ó bàjẹ́ gidigidi, ti o si jẹ wipe nitori àìṣedẽdé yin! Àti nítorí ìkẹdùn àti ohùnréré- ẹkún mi ẹ̀yin péjọ, ẹnu sì yà nyín; bẹ̃ni, ẹ̀yin ní ìdí tí ó pọ̀ láti yanu; bẹ̃ni, ẹnu níláti yà nyín nítorípé ẹ̀yin ti jọwọ́ ara nyín sílẹ̀ tí èṣù sì ti lágbára tí ó tóbi lórí ọkàn nyín. Bẹ̃ni, báwo ni ẹ̀yin ṣe ti fi ara nyín sílẹ̀ fún ẹ̀tàn ẹnití nwá ọ̀nà ìpàdánù ẹ̀mí nyín sínú ìrora ayérayé àti ìbànújẹ́ aláìlópin? A! ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà! Ẹ̀yin ó ha ṣe ku? Ẹ yípadà, ẹ yípadà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run nyín. Kíni ìdí rẹ̀ tí ó fi kọ̀ nyín sílẹ̀? Èyí rí bẹ̃ nítorípé ẹ̀yin sé ọkàn nyín le; bẹ̃ni ẹ̀yin sì kọ̀ láti fi eti si ohùn olùṣọ́-àgùtàn rere nnì; bẹ̃ni, ẹ̀yin ruú sókè lati ìbínú sí nyín. Ẹ sì kíyèsĩ, kàkà kí ó kó nyín jọ, àfi bí ẹ̀yin yíò bá ronúpìwàdà, ẹ kíyèsĩ, yíò fọ́n nyín ká tí ẹ̀yin yíò sì di oúnjẹ fún ajá àti àwọn ẹranko ti o npẹran jẹ. A! báwo ni ẹ̀yin ha ṣe gbàgbé Ọlọ́run nyín ní ọjọ́ nã tí ó ti gbà nyín? Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, láti rí èrè gbà ni, láti gba ìyìn láti ọwọ́ ọmọ ènìyàn, bẹ̃ni, àti kí ẹ̀yin lè rí wúrà àti fàdákà gbà. Ẹ̀yin sì ti kó ọkàn nyín lé àwọn ọrọ̀ àti ohun asán ayé yĩ, nítorí èyítí ẹ̀yin nṣe ìpànìyàn, àti ìkógun, àti olè jíjà, tí ẹ sì njẹ́rĩ èké sí aládũgbò nyín, tí ẹ sì nṣe onírurú àìṣedẽdé. Àti nítorí ìdí èyí ni ẹ̀yin yíò ṣe ṣègbé àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà. Nítorítí bí ẹ̀yin kò bá ní ronúpìwàdà, ẹ kíyèsĩ, ìlú-nlá yĩ, àti gbogbo àwọn ìlú-nlá tí ó wà ní àyíká, tí ó wà nínú ilẹ̀ ìní wa, ni nwọn yíò gbà, tí ẹ̀yin kò sì ní ní àyè nínú nwọn; nítorítí ẹ kíyèsĩ, Olúwa kò ní fún nyín lágbára, gẹ́gẹ́bí òun ti ṣe títí dé àkokò yĩ, láti lè dojúkọ àwọn ọ̀tá nyín. Nítorí ẹ kíyèsĩ, báyĩ ni Olúwa wi: Èmi kò ní fifún ènìyàn búburú nínú agbára mi, fún ọ̀kan ju òmíràn lọ, àfi fún àwọn tí ó ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, tí nwọ́n sì tẹ́tísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi. Nítorínã nísisìyí, èmi rọ̀ nyín láti kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé yíò sàn fún àwọn ará Lámánì j ù nyín l ọ à f i b í ẹ̀yin bá ronúpìwàdà. Nítorí ẹ kíyèsĩ, nwọ́n jẹ́ olódodo jù nyín lọ, nítorítí nwọ́n kò ṣẹ̀ sí ìmọ̀ nlá nì èyítí ẹ̀yin ti rí gbà; nítorínã ni Ọlọ́run yíò fi ṣãnú fún nwọn; bẹ̃ni, yíò mú kí ọjọ́ nwọn gùn yíò sì mú kí iní-ọmọ nwọn ó pọ̀ síi, àní nígbàtí a ó pa nyín run pátápátá àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà. Bẹ̃ni, ègbé ni fún nyín nítorí ìwà ìríra nnì èyítí ó ti wọ ãrín nyín; tí ẹ̀yin sì ti fọwọ́sowọ́pọ̀ nínú rẹ, bẹ̃ni nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn nnì èyítí Gádíátónì dá sílẹ̀! Bẹ̃ni, ègbé yio wa si ori yin nítorí ìwà ìgbéraga nnì èyítí ẹ̀yin ti gba lãyè láti wọnú ọkàn nyin, èyítí ó ti ru nyín sókè kọjá èyítí ó dára nítorí ọrọ̀ nyín tí ó pọ̀ púpọ̀ jùlọ! Bẹ̃ni, ègbé ni fún nyín nítorí ìwà búburú àti ìwà ìríra nyín! Àti wípé àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà ẹ̀yin yíò parun; bẹ̃ni, nwọn yíò gba ilẹ̀ nyín pãpã lọ́wọ́ nyín, nwọn yíò sì pa nyín run kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ kíyèsĩ nísisìyí, èmi kò sọ àwọn ohun yĩ nípa ìmọ̀ ara mi, nítorípé kĩ ṣe tìkarami ni èmi ṣe mọ́ àwọn ohun yĩ; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, mo mọ̀ pé òtítọ́ ni àwọn ohun wọ̀nyí í ṣe nítorípé Olúwa Ọlọ́run ti sọ nwọ́n di mímọ̀ fún mi, nítorínã ni èmi ṣe jẹ́rĩ pé nwọn yíò rí bẹ̃. 8 Àwọn adájọ́ oníbàjẹ́ wá ọ̀nà láti ru àwọn ènìyàn lọ́kàn sókè sí Nífáì—Ábráhámù, Mósè, Sénọ́sì, Sénọ́kì, Ésíásì, Isaiah, Jeremíàh, Léhì, àti Nífáì gbogbo nwọn ni ó jẹ́rĩ nípaKrístì—Nípa ìmísí Nífáì kéde pípa tí nwọn yíò pa adájọ́ àgbà. Ní ìwọ̀n Ọdun 23 sí 21 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Nífáì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ẹ kíyèsĩ, àwọn ọkùnrin kan wà tí nwọn jẹ́ adájọ́, tí nwọ́n tún wà nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn Gádíátónì, nwọ́n sì bínú nwọ́n sí kígbe jáde láti takọ́ nwọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn nã pé: Èéṣe tí ẹ̀yin kò mú ọkùnrin yĩ kí ẹ sì múu wá, kí àwa ó lè dájọ́ fún un ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ èyítí ó ti ṣẹ̀? Báwo ni ẹ̀yin ṣe nwo ọkùnrin yĩ, àti tí ẹ̀yin nfetísílẹ̀ síi bí ó ṣe nkẹ́gàn àwọn ènìyàn yĩ àti òfin wa? Nítorí ẹ kíyèsĩ, Nífáì ti bá nwọn sọ̀rọ̀ nípa ìdíbàjẹ́ òfin nwọn; bẹ̃ni, àwọn ohun púpọ̀ ni Nífáì sọ èyítí a kò lè kọ; àti pé kò sí ohun tí ó sọ tí ó lòdì sí òfin Ọlọ́run. Àwọn adájọ́ nnì sì bínú síi nítorípé ó sọ̀rọ̀ òtítọ́ sí nwọn nipa àwọn iṣẹ́ òkùnkùn t í nwọn nṣe ní ìkọ̀kọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọn kò lè fi ọwọ́kàn án, nítorítí nwọ́n bẹ̀rù pé àwọn ènìyàn nã yíò kígbe takò nwọ́n. Nítorínã nwọ́n kígbe sí àwọn ènìyàn nã, wípé: Èéṣe ẹ̀yin ṣe gba ọkùnrin yĩ lãyè láti kẹ́gàn wa? Nítorí ẹ kíyèsĩ ó ti dá àwọn ènìyàn yĩ lẹ́bi, àní sí ìparun, bẹ̃ni, àti pẹ̀lú pé nwọn yíò gba àwọn ìlú-nlá wa títóbi wọ̀nyí lọ́wọ́ wa, tí àwa kò sì ní ní ìpín nínú nwọn. Àti nísisìyí àwa sì ti mọ̀ pé eleyĩ kò lè rí bẹ̃, nítorí kíyèsĩ, alágbára ni àwa í ṣe, àwọn ìlú-nlá wa sì tóbi, nítorínã àwọn ọ̀ta wa kò lè lágbára lé wa lórí. Ó sì ṣe tí nwọ́n sì ru àwọn ènìyàn nã sókè ní ìbínú sí Nífáì, tí nwọ́n sì mú kí ìjà ó bẹ̀rẹ̀ lãrín nwọn; nítorítí àwọn kan wà tí ó kígbe wípé: Ẹ fi ọkùnrin yĩ sílẹ̀, nítorítí ènìyàn rere ni í ṣe, àwọn ohun tí ó sì nsọ yíò ṣẹ ní tọ́tọ́ àfi bí àwa bá ronúpìwàdà; Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, gbogbo ìdájọ́ tí ó jẹ́rĩ sí yĩ ní yíò bá wa; nítorítí àwa mọ̀ pé ó ṣe ijẹrisi òdodo fún wa nípa àwọn àìṣedẽdé wa. Ẹ sì kíyèsĩ nwọ́n pọ̀, òun sì mọ́ ohun gbogbo tí yíò ṣẹ sí wa gẹ́gẹ́bí òun ti mọ̀ nípa àwọn àìṣedẽdé wa; Bẹ̃ni, ẹ sì kíyèsĩ, bí kò bá ṣe pé wòlĩ ni í ṣe òun kò lè ṣe ijẹrisi nípa àwọn ohun wọnnì. Ó sì ṣe tí a fi ipa mú àwọn ènìyàn nnì tí nwọ́n lépa láti pa Nífáì nítorítí nwọ́n bẹ̀rù, tí nwọn kò sì fi ọwọ́ kàn án; nítorínã ó sì tún bẹ̀rẹ̀sí bá nwọn sọ̀rọ̀, nígbàtí ó ríi pé òun ti rí ojú rere díẹ̀ nínú nwọn, tóbẹ̃ tí àwọn tí ó kù sì bẹ̀rù. Nítorínã ó tún níláti bá nwọn sọ̀rọ̀ síi pé: Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀yin kò ha ríi kà pé Ọlọ́run fi agbára fún ọkùnrin kan, àní Mósè, kí ó lu ojú omi Òkun Pupa, tí nwọ́n sì pínyà sí méjì, tóbẹ̃ tí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì, tí nwọn í ṣe bàbá nlá wa, lã kọjá lórí ilẹ̀ tí ó gbẹ, tí omi nã sì padé mọ́ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Égíptì tí ó sì gbé nwọn mì? Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, bí Ọlọ́run bá fi irú agbára báyĩ fún ọkùnrin yĩ, nítorínã ẽṣe tí ẹ̀yin ṣe nbá ara nyín jiyàn, tí ẹ wípé òun kò fún mi ní agbára tí èmi ófi mọ̀ nípa ìdájọ́ tí yíò bá nyín àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà? Ṣùgbọ́n, ẹ kíyèsĩ, kĩ ṣe pé ẹ̀yin sẹ́ ọ̀rọ̀ mi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin tún sẹ́ gbogbo ọ̀rọ̀ èyítí àwọn bàbá nlá wa ti sọ, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti ọkùnrin yĩ, Mósè, ti sọ, ẹnití a fi agbára nlá fún, bẹ̃ni, àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ nípa bíbọ̀ Messia nã. Bẹ̃ni, òun kò ha jẹ́rĩ wípé Ọmọ Ọlọ́run nã nbọ̀wá bí? Bí ó sì ti gbé ejò idẹ nnì sókè nínú aginjù, àní bẹ̃ni a ó gbé ẹnití nbọ̀wá sókè. Gbogbo àwọn tí yíò sì gbe ójú sókè wo ejò nã ni yíò yè, bẹ̃ni gbogbo àwọn tí yíò gbe ójú sókè wo Ọmọ Ọlọ́run nã pẹ̀lú ìgbàgbọ́, tí nwọ́n ní ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, lè yè, àní sí ayé nnì èyítí í ṣe ayérayé. Àti nísisìyí kíyèsĩ, kì í ṣe Mósè nìkan ni ó jẹrisi àwọn ohun yìi, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ pẹ̀lú, láti ìgbà rẹ̀ àní títí dé ìgbà Ábráhámù. Bẹ̃ni, ẹ sì kíyèsĩ, Ábráhámù ri nípa bíbọ̀ rẹ̀, ó sì kún fún inú dídùn ó sì yọ̀. Bẹ̃ni, ẹ sì kíyèsĩ èmi wí fún nyín, pé kĩ ṣe Ábráhámù nìkan ni ó mọ̀ nípa àwọn ohun yĩ, ṣùgbọ́n àwọn púpọ̀ ni ó wà ṣãjú ìgbà Ábráhámù tí a pè ní ti ẹgbẹ́ Ọlọ́run; bẹ̃ni, àní níti ipa Ọmọ rẹ̀; ó sì rí báyĩ kí a lè fi han àwọn ènìyàn nã, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ọdún sãjú bíbọ̀ rẹ̀, pé ìràpadà yíò wá bá nwọn. Àti nísisìyí èmi fẹ́ kí ẹ mọ̀, pé àní láti ìgbà Ábráhámù ni àwọn wòlĩ púpọ̀ ti jẹrisi àwọn ohun yĩ; bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, wòlĩ Sénọ́sì jẹ́rĩ pẹ̀lú ìgboyà; nítorínã ni nwọ́n sì fi pa á. Àti kí ẹ kíyèsĩ, Sénọ́kì pẹ̀lú, àti Ésíásì pẹ̀lú, àti Isaiah pẹ̀lú, àti Jeremíàh, (Jeremíàh ni wòlĩ kannã tí ó jẹrisi ìparun Jerúsálẹ́mù) àti nísisìyí àwa mọ̀ pé Jerúsálẹ́mù parun ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jeremíàh. A! njẹ́ nígbànã éṣe tí Ọmọ Ọlọ́run nã kò ha ní wá, ní ìbámu pẹ̀lú ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀? Àti nísisìyí njẹ́ ẹ̀yin yíò ha jiyàn pé a pa Jerúsálẹ́mù run? Njẹ́ ẹ̀yin yíò ha wípé a kò pa àwọn ọmọ Sẹdẹkíàh, gbogbo nwọn àfi Múlẹ́kì? Bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin kò ha ríi pé irú ọmọ Sẹdẹkíàh wà pẹ̀lú wa, àti pé a lé nwọn jáde kúrò nínú ìlẹ̀ Jerúsálẹ́mù? Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èyí nìkan kọ́— Nwọ́n lé bàbá wa Léhì jáde kúrò nínú Jerúsálẹ́mù nítorípé ó jẹrisi àwọn ohun wọ̀nyí. Nífáì pẹ̀lú jẹrisi àwọn ohun wọ̀nyí, àti pẹ̀lú èyítí ó pọ̀jù nínú àwọn bàbá nlá wa, àní títí dé àkokò yĩ; bẹ̃ni, nwọ́n ti jẹrisi bíbọ̀ Krístì, nwọ́n sì ti fi ojú sọ́nà, nwọ́n sì ti yọ̀ nínú ọjọ́ rẹ̀ tí nbọ̀wá. Ẹ sì kíyèsĩ, Ọlọ́run ni í ṣe, ó sì wà pẹ̀lú nwọn, ó sì fi ara rẹ̀ hàn sí nwọn, pé òun ni ó rà nwọ́n padà; nwọ́n sì fi ògo fún un, nítorí èyítí nbọ̀wá. Àti nísisìyí, nítorípé ẹ̀yin mọ́ àwọn ohun wọ̀nyí tí ẹ kò sì lè sẹ́ nwọn àfi bí ẹ̀yin ó bá purọ́, nítorínã ni ẹ̀yin ti ṣẹ̀ nínú èyí, nítorítí ẹ̀yin ti kọ gbogbo nkan wọ̀nyí, l’áìṣírò ẹ̀yin ti rí ẹ̀rí tí ó pọ̀ gbà; bẹ̃ni, àní ẹ̀yin ti rí ohun gbogbo gbà, àwọn ohun tí ó wà lọ́rùn, àti ohun gbogbo tí ówà láyé, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí pé òtítọ́ ni nwọ́n í ṣe. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti kọ òtítọ́, ẹ̀yin sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run nyín mímọ́; àti pãpã ní àkokò yĩ, èyítí ẹ̀yin ìbá to ìṣura jọ fun ara nyín ní ọ̀run, níbití ohunkóhun kò lè bàjẹ́, àti níbití ohunkóhun tí kò mọ́ kò lè wà; ẹ̀yin nkó ìbínú jọ fún ara nyín de ọjọ́ ìdájọ́. Bẹ̃ni, àní ní àkokò yĩ, ẹ̀yin nmúrasílẹ̀, nítorí àwọn ìwà ìpànìyàn nyín àti ìwà àgbèrè àti ìwà búburú nyín, de ìparun ayérayé; bẹ̃ni, àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà yíò dé bá nyín láìpẹ́ ọjọ́. Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ ó ti dé tán àní sí ẹ̀hìn ilẹ̀kùn nyín; bẹ̃ni, ẹ lọ sí órí ìtẹ́ ìdájọ́ nyín, kí ẹ sì ṣe ìwádĩ; ẹ sì kíyèsĩ, nwọ́n ti pa onidajọ nyín, ó sì dùbúlẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀; arákùnrin rẹ̀ ni ó sì pã, ẹnití ó nlépa láti wà lórí ìtẹ́ ìdájọ́. Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn méjẽjì wà nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn nyín nnì, ti olùdásílẹ̀ jẹ Gádíátónì àti ẹni búburú nnì tí nlépa láti pa ọkàn àwọn ènìyàn run. 9 Àwọn oníṣẹ́ rí adájọ́ àgbà tí ó ti kú lórí ìtẹ́ ìdájọ́—Nwọ́n fi nwọ́n sínú tũbú, nwọ́n sì tún tú nwọn sílẹ̀—Nípa ìmísí Nífáì fi Síátúmì hàn bĩ apànìyàn nã—Díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn nã gba Nífáì gẹ́gẹ́bí wòlĩ. Ní ìwọ̀n ọdún 23–21 kí a tó bí Olúwa wa. Ẹ kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Nífáì ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àwọn kan tí nwọ́n wà lãrín nwọn sáré lọ sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́; bẹ̃ni, àní àwọn marun ni ó lọ, nwọ́n sì wí lãrín ara nwọn, bí nwọ́n ṣe nlọ pé: Ẹ kíyèsĩ, nísisìyí àwa yíò mọ̀ dájúdájú bóyá wòlĩ ni ọkurin yĩ tí Ọlọ́run sì pãláṣẹ fún un láti sọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun ìyanu irú èyí fún wa. Ẹ kíyèsĩ, àwa kò gbàgbọ́ pé ó pãláṣẹ fún un; bẹ̃ni, àwa ko gbàgbọ́ pé wòlĩ ni; bíótilẹ̀ríbẹ̃, bí ohun yĩ tí ó sọ nípa adájọ́ àgbà bá jẹ́ òtítọ́, pé ó ti kú, nígbànã ni àwa yíò gbàgbọ́ pé òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yókù tí ó ti sọ. Ó sì ṣe tí nwọ́n sáré tagbáratagbára, tí nwọ́n sì wọlé sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́; ẹ sì kíyèsĩ, adájọ́ àgbà nã ti ṣubú lulẹ̀, ó sì wà nínú ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, nígbàtí nwọ́n r í èyí ẹnu yà nwọ́n gidigidi, tóbẹ̃ tí nwọ́n ṣubú lulẹ̀; nítorítí nwọn kò gba ọ̀rọ̀ tí Nífáì sọ nípa adájọ́-àgbà gbọ́. Ṣùgbọ́n nísisìyí nígbàtí nwọ́n rí ohun yĩ nwọ́n gbàgbọ́, ẹ̀rù sì bà nwọ́n pé gbogbo ìdájọ́ tí Nífáì ti sọ nípa rẹ̀ yíò dé bá àwọn ènìyàn nã; nítorínã ni nwọ́n ṣe wárìrì, tí nwọ́n sì ṣubú lulẹ̀. Nísisìyí, ní kété tí nwọ́n ti pa adájọ́ nã—arákùnrin rẹ̀ ni ó sì gún un lọ́bẹ nínú ẹ̀wù tí ó wọ̀ tí ẹnìkẹ́ni kò lè dáa mọ̀, ó sì sálọ, àwọn ìránṣẹ́ nã sì sáré lọ í sọ fún àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n sì nkígbe ìpàniyan lãrin nwọn; Ẹ sì kíyèsĩ àwọn ènìyàn nã sì kó ara nwọn jọ sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́ nã—ẹ sì kíyèsĩ, sí ìyàlẹ́nu nwọn, nwọ́n rí àwọn ọkùnrin marun nnì tí nwọ́n ti ṣubú lulẹ̀. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, àwọn ènìyàn nã kò mọ́ ohunkóhun nípa àwọn ọ̀gọ̣́rọ̀ ènìyàn tí nwọ́n ti pèjọ́ nínú ọgbà Nífáì; nítorínã nwọ́n sọ lãrín ara nwọn pé:Àwọn ọkùnrin yĩ ni àwọn tí ó pa onidajọ, Ọlọ́run sì ti lù nwọ́n tí nwọn kò lè sálọ kúrò lọ́wọ́ wa. Ó sì ṣe tí nwọ́n mú nwọn, nwọ́n sì dè nwọ́n nwọ́n sì jù nwọ́n sínú tũbú. Nwọ́n sì ránṣẹ́ jáde lãrín àwọn ènìyàn nã pé nwọ́n ti pa adájọ́, àti pé nwọ́n ti mú àwọn apànìyàn nã nwọ́n sì ti jù nwọ́n sínú tũbú. Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì tí àwọn ènìyàn nã sì péjọ pọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti gbãwẹ̀, níbití nwọ́n gbé nsin òkú onidajọ-àgbà olókìkí nnì tí nwọ́n pa. Àti báyĩ pẹ̀lú ni àwọn onidajọ nnì tí nwọ́n wà ní ọgbà Nífáì, tí nwọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, nã péjọ pọ̀ sí ibi ìsìnkú nã. Ó sì ṣe tí nwọ́n nbẽrè lãrín àwọn ènìyàn nã, wípé: Àwọn marun nã tí a rán láti lọ ṣe ìwãdí nípa adájọ́ àgbà nã bóyá ó ti kú dà? Nwọ́n sì dáhùn nwọ́n wípé: Nípa àwọn marun yĩ ti ẹ̀yin ní ẹ ran níṣẹ́, àwa kò mọ̀; ṣùgbọ́n àwọn marun kan wà tí nwọn í ṣe apànìyàn, tí àwa sì ti jù sínú tũbú. Ó sì ṣe tí àwọn onidajọ nã ní kí nwọn mú nwọn wá; nwọn sì mú wọn wá, sì kíyèsĩ àwọn ni àwọn marun tí nwọ́n ti rán níṣẹ́; ẹ sì kíyèsĩ àwọn onidajọ nã bẽrè lọ́wọ́ nwọn láti mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ nã, nwọ́n sì sọ fún nwọn nípa gbogbo ohun tí àwọn tí ṣe, wípé: Àwa sáré a sì dé ibi ìtẹ́ ìdájọ́, nígbàtí àwa sì rí ohun gbogbo àní bí Nífáì ti jẹrisi, ẹnu yà wá tóbẹ̃ tí àwa ṣubú lu ilẹ̀; nígbàtí àwa sì ta jí kúrò nínú ìyàlẹ́nu wa, kíyèsĩ nwọn ti jù wá sínú tũbú. Nísisìyí, nípa ti pípa ọkùnrin yĩ, àwa kò mọ́ ẹnití ó ṣeé; ohun tí àwa mọ̀ kòju èyí, a sáré a sì wá gẹ́gẹ́bí ẹ̀yin ti fẹ́, kí ẹ sì kíyèsĩ ó ti kú, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Nífáì. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn onidajọ nã sì ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ nã fún àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n sì kígbe tako Nífáì, wípé: Ẹ kíyèsĩ, àwa mọ̀ wípé Nífáì yĩ ti gbìmọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan láti pa onidajọ nã, lẹ́hìn nã ni yíò sì sọ fún wa, láti lè yí wa padà sí ìgbàgbọ́ tirẹ̀, láti lè gbé ara rẹ̀ sókè pé ènìyàn nlá ni òun, ẹni tí Ọlọ́run yàn, tí í sì í ṣe wòlĩ. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, àwa yíò wá ọkùnrin yĩ rí, òun yíò sì jẹ́wọ́ ẹ̀bi rẹ̀ tí yíò sì fi ẹnití ó pa onidajọ yĩ hàn wá. Ó sì ṣe tí nwọ́n tú àwọn marun nã sílẹ̀ ní ọjọ́ ìsìnkú nã. Bíótilẹ̀ríbẹ̃ nwọ́n bá àwọn onidajọ nã wí ní ti ọ̀rọ̀ tí nwọ́n ti sọ tako Nífáì, nwọ́n sì bá nwọn jà lọ́kọ̣́kan tóbẹ̃ tí nwọ́n sì dàmú nwọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n mú kí nwọn ó mú Nífáì kí nwọn ó sì dẽ kí nwọn sì múu wá síwájú àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bĩ lẽrè lonírurú ọnà láti lè múu tako ara rẹ̀, tí nwọn ó sì pè é lẹ́jọ́ ikú— Nwọ́n sì wí fún un pé: Ìwọ wà ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan; tani ẹni nã tí ó ṣe ìpànìyàn yĩ? Nísisìyí sọ fún wa, kí ó sì gbà pé ó jẹ̀bi; nwọ́n tún wípé: Kíyèsĩ owó rẽ; àti pẹ̀lú pé àwa yíò dá ẹ̀mí rẹ sí bí ìwọ bá lè sọ fún wa, tí ìwọ sì jẹ́wọ́ sí àdéhùn tí ìwọ ti ṣe pẹ̀lú rẹ̀. Ṣùgbọ́n Nífáì wí fún nwọn pe: A! ẹ̀yin aláìmòye ènìyàn yĩ, ẹ̀yin aláìkọlà ní ọkàn ènìyàn yĩ, ẹ̀yin afọ́jú ènìyàn, àti ọlọ́rùn líleènìyàn, njẹ́ ẹ̀yin ha mọ̀ bí yíò ti pẹ́ tó tí Olúwa Ọlọ́run nyín yíò gbà nyín lãyè láti tẹ̀síwájú nínú ipa ẹ̀ṣẹ̀ nyín yĩ? A! ó yẹ kí ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀sí pohùnréré ẹkún kí ẹ sì kẹ́dùn ọkàn, nítorí ìparun nlá nnì tí ó dúró dè nyín ní àkokò yĩ, àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà. Ẹ kíyèsĩ ẹ̀yin sọ wípé mo ti ni àdéhùn pẹ̀lú ẹnìkan pé kí ó pa Sísórámù, onidajọ-àgbà wa. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín, pé nítorítí mo jẹrisi nyín kí ẹ̀yin ó lè mọ̀ nípa ohun yĩ ni ẹ̀yin ṣe sọ eleyĩ; bẹ̃ni, àní sí ijẹrisi fún nyín, pé èmi mọ̀ nípa ìwà búburú àti ìwà ẽrí èyítí ó wà lãrín nyín. Àti nítorítí èmi ṣe eleyĩ, ẹ̀yin ní èmi ti ní àdéhùn pẹ̀lú ẹnìkan láti ṣe nkan yĩ; bẹ̃ni, nítorípé mo fi àmì yĩ hàn yín ẹ̀yin nbínú sí mi, ẹ sì nlépa láti pa mi run. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èmi yíò fi àmì míràn hàn nyín, láti ríi bóyá ẹ̀yin yíò lépa láti pa mí run nínú ohun yĩ. Ẹ kíyèsĩ mo wí fún nyín: Ẹ lọ sí ilé Síátúmì, ẹnití í ṣe arákùnrin Sísórámù, kí ẹ sì wí fún un pé— Njẹ́ Nífáì, wòlĩ èké nnì, tí nsọ ìsọtẹ́lẹ̀ ohun búburú nípa àwọn ènìyàn yĩ, ha bá ọ ní àdéhùn, nínú èyítí o pa Sísórámù, ẹnití í ṣe arákùnrin rẹ bí? Ẹ sì kíyèsĩ, yíò wí fún nyín pe, Rárá. Ẹ̀yin yíò sì wí fún un pé: Ìwọ ha pa arákùnrin rẹ bí? Òun yíò sì dúró ní ìbẹ̀rù, kò sì ní mọ́ ohun tí yíò sọ. Ẹ sì kíyèsĩ, òun yíò sẹ́ pípa arákùnrin rẹ̀; òun yíò sì ṣe bí ẹnití ẹnu yà; bíótilẹ̀ríbẹ̃, òun yíò wí fún nyín pé aláìṣẹ̀ ni òun í ṣe. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin yíò ṣe àyẹ̀wò ara rẹ̀ ẹ ó sì rí ẹ̀jẹ̀ lã ẹ̀wù ìlekè rẹ̀. Nígbàtí ẹ̀yin bá sì ti rí èyí, ẹ̀yin yíò wípé: Níbo ni ẹ̀jẹ̀ yĩ ti wá? Àwa kò ha mọ̀ wípé ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ni í ṣe bí? Nígbànã ni yíò wárìrì, awọ ojú rẹ yíò di ràndànràndàn, àní bí ẹnití ikú ti dé bá. Nígbànã ni ẹ̀yin yíò wípé: Nítorí ìbẹ̀rù yĩ àti ràndànràndàn tí ó dé bá ojú rẹ yĩ, kíyèsĩ, àwa mọ̀ pé o jẹ̀bi. Nígbànã ni ẹ̀rù tí ó tóbi síi yíò dé bã; nígbànã ni yíò sì jẹ́wọ́ fún nyín, tí yíò sì ṣíwọ́ sísẹ́ tí ó nsẹ́ pé òun kọ́ ni ó ṣe ìpànìyàn yĩ. Nígbànã ni yíò wí fún un yín, pé èmi Nífáì kò mọ́ ohunkóhun nípa ọ̀rọ̀ yĩ àfi bí a bá fií fún mi nípa agbára Ọlọ́run. Nígbànã ni ẹ̀yin yíò sì mọ̀ pé olotitọ ènìyàn ni èmi í ṣe, àti pé Ọlọ́run ni ó rán mi sí nyín. Ó sì ṣe tí nwọ́n sì lọ, nwọ́n sì ṣe, àní gẹ́gẹ́bí Nífáì ti wí fún nwọn. Ẹ sì kíyèsĩ, òtítọ́ sì ni àwọn ohun tí ó sọ; nítorítí gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì sẹ́; àti pẹ̀lú gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì jẹ́wọ́. Nwọ́n sì mú u láti fi hàn kedere pé òun tìkararẹ̀ ni apànìyàn nã n í t ọ́ t ọ́ , tóbẹ̃ t í nwọ́n fi tú àwọn marun nnì sílẹ̀, àti Nífáì pẹ̀lú. Àwọn kan nínú àwọn ará Nífáì gba àwọn ọ̀rọ̀ Nífáì gbọ́; àwọn kan sì wà pẹ̀lú tí ó gbàgbọ́ nítorí ẹ̀rí àwọn marun nnì, nítorítí nwọ́n ti yí padà nígbàtí nwọ́n wà nínú tũbú. Àti nísisìyí àwọn kan wà lãrín àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n wípé wòlĩ ni Nífáì í ṣe. Àwọn míràn sì wà tí nwọ́n wípé: Ẹ kíyèsĩ, òrìṣà kan ni í ṣe, nítorítí bí kò bá ṣe pé òrìṣà kan ni í ṣe kò lè mọ̀ nípa ohun gbogbo. Nítorí ẹ kíyèsĩ, ó ti sọ gbogbo èrò ọkàn wa fún wa, àti pẹ̀lú ó ti sọ àwọn nkan fún wa; àti pãpã ó mú kí àwa ó mọ́ ẹnití ó pa adájọ́-àgbà wa ní tọ́tọ́. 10 Olúwa fún Nífáì ní agbára èdìdì—A fún un lágbára láti lè dè àti láti lè tú sílẹ̀ láyé àti lọ́run—Ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn nã láti ronúpìwàdà tàbí kí nwọ́n ṣègbé—Ẹ̀mi gbé e láti ọ̀pọ̀ ènìyàn dé ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ní ìwọ̀n ọ́dun 21 sí 20 kí a tó bí Olúwa wa. Ó sì ṣe tí ìyapa wà lãrín àwọn ènìyàn nã, tóbẹ̃ tí nwọ́n pín ara nwọn síhin àti sọ́hun tí nwọ́n sì pínyà, tí nwọ́n sì fi Nífáì sílẹ̀, bí ó ṣe dúró lãrín nwọn. Ó sì ṣe tí Nífáì bá tirẹ̀ lọ sí ọ̀nà ilé rẹ̀, tí ó nṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tí Olúwa ti fi hàn síi. Ó sì ṣe bí ó ti nṣe àṣàrò yĩ— ọkàn rẹ̀ sì rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn ará Nífáì nã, àwọn iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ ti òkùnkùn nwọn, àti ìpànìyàn nwọn, àti ìkógun tí nwọn nṣe, àti onírurú àìṣedẽdé—ó sì ṣe bí ó ti nṣe àṣàrò ní ọkàn rẹ̀ báyĩ, ẹ kíyèsĩ, ohùn kan tọ̣́ wá tí ó wípé: Ìbùkún ni fún ọ, Nífáì, nítorí àwọn ohun nì tí ìwọ ti ṣe; nítorítí èmi ti rí bí ìwọ ti nsọ ọ̀rọ̀ mi jáde láìkãrẹ̀, èyítí mo fi fún ọ, fún àwọn ènìyàn yĩ. Ìwọ kò sì bẹ̀rù nwọn, ìwọ kò sì wá ìpamọ́ fún ẹ̀mí ti ara rẹ, ṣùgbọ́n ó lépa ìfẹ́ mi, àti láti pa òfin mi mọ́. Àti nísisìyí, nítorípé ìwọ ṣe eleyĩ láìkãrẹ̀, kíyèsĩ, èmi yíò bùkún fún ọ títí láé; èmi yíò sì fún ọ ní agbára nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe, ní ìgbàgbọ́ àti nínú iṣẹ́; bẹ̃ni àní tí ohun gbogbo yíò di ṣíṣe gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ; nítorítí ìwọ kì yíò bẽrè èyítí ó tako ìfẹ mi. Kíyèsĩ, ìwọ ni Nífáì, èmi sì ni Ọlọ́run. Kíyèsĩ, èmi sọ̣́ jáde sí ọ níwájú àwọn ángẹ́lì mi, pé ìwọ yíò lágbára lórí àwọn ènìyàn yĩ, ìwọ yíò sì fi ìyàn bá ilẹ̀ nã jà, àti pẹ̀lú àrùn, àti ìparun, gẹ́gẹ́bí ìwà búburú àwọn ènìyàn yĩ. Kíyèsĩ, mo fi agbára fún ọ, pé ohunkóhun tí ìwọ yíò fi èdìdì dì ní ayé ni a ó fi èdìdì dì ní ọ̀run; àti ohunkóhun tí ìwọ yíò tú sílẹ̀ ní ayé ni a ó tú sílẹ̀ ní ọ̀run; báyĩ ni ìwọ yíò sì ní agbára lãrín àwọn ènìyàn yĩ. Àti báyĩ, bí ìwọ yíò bá wí fún tẹ́mpìlì yĩ pé kí ó ya sí méjì, yíò sì rí bẹ̃. Àti bí ìwọ yíò bá wí fún òkè yĩ, Wó lulẹ̀ kí ó sì di pẹ̀tẹ́lẹ̀, yíò sì rí bẹ̃. Sì kíyèsĩ, bí ìwọ yíò bá wípé kí Ọlọ́run kí ó kọlũ àwọn ènìyàn yĩ, yíò sì rí bẹ̃. Àti nísisìyí, kíyèsĩ, mo p láṣẹ fún ọ, pé kí o lọ kí o sì sọ fún àwọn ènìyàn yĩ, pé báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí, ẹnití tí íṣe Olódùmarè: Afi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà a ó kọlũ nyín, àní sí ìparun. Ẹ sì kíyèsĩ, ó sì ṣe nígbàtí Olúwa ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Nífáì, ó dúró kò sì lọ sínú ilé ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ó padà sí ọ́dọ̀ àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã tí nwọ́n titúká lórí ilẹ̀ nã, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èyítí a ti sọ fún un fún nwọn, nípa ìparun nwọn bí nwọn kò bá ronúpìwàdà. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, l’áìṣírò Nífáì ṣe ohun ìyanu níti sísọ fún nwọn nípa ikú onidajọ-àgbà, nwọ́n sì sé àyà nwọn le nwọn kò sì tẹ́tísí sí ọ̀rọ̀ Olúwa. Nítorínã Nífáì sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún nwọn, wípé: Afi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà, báyĩ ni Olúwa wí, a ó kọlũ nyín àní sí ìparun. Ó sì ṣe nígbàtí Nífáì ti sọ ọ̀rọ̀ nã fún nwọn tán, ẹ kíyèsĩ, nwọ́n sì tún sé àyà nwọn le nwọn kò sì tẹ́tísí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀; nítorínã nwọ́n nkẹ́gàn rẹ̀, nwọ́n sì nwá ọ̀nà tí nwọn ó fi múu, tí nwọn ó sì jũ sínú túbú. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, agbára Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, nwọ́n kò sì lè múu láti jù ú sínú tũbú, nítorítí Ẹ̀mí múu lọ tí ó sì gbée kúrò lãrín nwọn. Ó sì ṣe pé báyĩ ni ó nlọ nínú Ẹ̀mí, láti ọ̀pọ̀ ènìyàn dé ọ̀pọ̀ ènìyàn, tí ó nsọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àní títí ó fi sọọ́ fún gbogbo nwọn, tàbí tí ó fi ránṣẹ́ lãrín àwọn ènìyàn nã gbogbo. Ó sì ṣe tí nwọn kọ̀ láti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀; asọ̀ sì bẹ̀rẹ̀sí wà, tóbẹ̃ tí ìpinyà fi wà lãrín nwọn tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa ara nwọn pẹ̀lú idà. Báyĩ sì ni ọdún kọkànlélãdọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí. 11 Nífáì rọ Olúwa kí ó fi ìyàn rọ́pò ogun jíjà lãrín nwọn—Ọ̀pọ̀ ènìyàn parun—Wọ́n ronúpìwàdà, Nífáì sì bẹ Olúwa láìsinmi fún òjò—Nífáì àti Léhì gba ìfihàn púpọ̀—Àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ilẹ̀ nã. Ní ìwọ̀n ọdún 20 sí 16 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ọdún kejìlélãdọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ tí àwọn asọ̀ nã pọ̀ síi, tóbẹ̃ tí ogun wà jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã lãrín gbogbo àwọn ènìyàn Nífáì. Àwọn ọlọ́ṣà ẹgbẹ́ òkùnkùn yĩ sì ni ó nṣe iṣẹ́ ìparun àti ìwà búburú yĩ. Ogun yĩ sì wà ní gbogbo ọdún nã; àti nínú ọdún kẹtàlélãdọ́rin ni ó wà pẹ̀lú. Ó sì ṣe nínú ọdún yĩ tí Nífáì kígbe pe Ọlọ́run wípé: A! Olúwa, máṣe jẹ́ kí àwọn ènìyàn yĩ ó parun nípasẹ̀ idà ṣùgbọ́n A! Olúwa, dípò èyí jẹ́ kí ìyàn kí ó wà lórí ilẹ̀ nã, láti ta nwọ́n jí sí ìrántí Olúwa Ọlọ́run nwọn, bóyá nwọn yíò ronúpìwàdà kí nwọ́n sì yípadà sí ọ̀dọ̀ rẹ. Ó sì rí bẹ̃, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Nífáì. Ìyàn nlá sì wà lórí ilẹ̀ nã, lãrín gbogbo àwọn ènìyàn Nífáì. Àti báyĩ nínú ọdún kẹrìnlélãdọ́rin ìyàn nã tẹ̀síwájú, iṣẹ́ ìparun sì dópin ṣùgbọ́n ó pọ̀ nípasẹ̀ ìyàn. Iṣẹ́ ìparun yĩ sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú nínú ọdún karundinlọgọrin. Nítorítí a kọlũ ilẹ̀ tí ó sì gbẹ, tí kò sì mú irúgbìn jáde ní àkokò irúgbìn gbogbo ilẹ̀ ni a sì kọlù, àní lãrín àwọn ará Lámánì àti lãrín àwọn ará Nífáì, tí a sì kọlù nwọ́n tí nwọ́n sì parun ní ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ní àwọn apá ilẹ̀ nã níbití àwọn ènìyàn nã ti ṣe búburú jùlọ. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã ríi pé ìyàn fẹ́rẹ̀ pa nwọ́n run, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí rántí Olúwa Ọlọ́run nwọn; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí rántí àwọn ọ̀rọ̀ Nífáì. Àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú àwọn adájọ́-àgbà nwọn àti àwọn olórí nwọn, pé wọn yíò wí fún Nífáì pe: Kíyèsĩ, àwa mọ̀ wípé ẹni Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe, nítorínã ké pe Olúwa Ọlọ́run wa kí ó mú ìyàn yĩ kúrò lọ́dọ̀ wa kí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ìwọ ti sọ nípa ìparun wa má bã di mímú ṣẹ. Ó sì ṣe tí àwọn onidajọ nã sì wí fún Nífáì ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí nwọ́n fẹ́. Ó sì ṣe nígbàtí Nífáì ríi pé àwọn ènìyàn nã ti ronúpìwàdà tí nwọ́n sì rẹ̀ ara nwọn sílẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ó tún kígbe pe Olúwa, wípé: A! Olúwa, kíyèsĩ àwọn ènìyàn yìi ti ronúpìwàdà; nwọ́n sì ti mú àwọn ẹgbẹ́ Gádíátónì kúrò lãrín nwọn tóbẹ̃ tí nwọn kò sí mọ́, nwọ́n sì ti ri àwọn ìlànà iṣẹ́ òkùnkùn nwọn bọlẹ̀. Nísisìyí, A! Olúwa, nítorí ìwà ìtẹríba nwọn yĩ kí ìwọ kí ó mú ìbínú rẹ̀ kúrò, kí o sì ni ìtùnù nínú ìparun àwọn ènìyàn búburú nnì tí ìwọ ti parun. A! Olúwa, kí ìwọ kí ó mú ìbínú rẹ kúrò, bẹ̃ni, gbígbóná ìbínú rẹ̀, kí ó sì mú kí ìyàn yĩ ó dáwọ́dúró lórí ilẹ̀ yĩ. A! Olúwa, kí ìwọ ó fetísílẹ̀ sí mi, kí o sì mú kí ó rí bẹ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ mi, kí o sì mú kí òjò kí ó rọ̀ sí órí ilẹ̀ ayé kí ó lè mú èso jáde, àti àwọn irúwó rẹ̀ ní àkokò irúwó. A! Olúwa, ìwọ fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi nígbàtí mo wípé, Jẹ́ kí ìyàn kí ó wa, kí ìparun nípasẹ̀ idà ó dáwọ́dúró; èmi sì mọ̀ wípé ìwọ yíò ṣẽ àní ní ìgbà yĩ, fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, nítorítí ìwọ wípé: Bí àwọn ènìyàn yĩ bá ronúpìwàdà èmi yio dá nwọn sí. Bẹ̃ni, A! Olúwa, ìwọ sì ríi pé nwọ́n ti ronúpìwàdà, nítorí ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn àti ìparun tí ó ti bá nwọn. Àti nísisìyí, A! Olúwa ìwọ kì yíò ha mú ìbínú rẹ kúrò, kí o sì tún dán nwọn wò bóyá nwọn yíò sìn ọ́ bí? Bí ó bá sì rí bẹ̃, A! Olúwa, ìwọ lè bùkún nwọn gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ìwọ ti sọ. Ó sì ṣe ní ọdún kẹrìndínlọ́gọ́rin Olúwa sì mú ìbínú rẹ kúrò lórí àwọn ènìyàn nã, tí ó sì mú kí òjò ó rọ̀ sí órí ilẹ̀, tóbẹ̃ tí ó mú èso rẹ̀ jáde ní àkokò rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó mú irúwó rẹ̀ jáde ní àkókò irúwó rẹ̀. Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ènìyàn nã yọ̀ nwọ́n sì fi ògo fún Ọlọ́run, gbogbo orí ilẹ̀ nã sì kún fún ayọ̀; nwọn kò sì lépa lati pa Nífáì mọ́, ṣùgbọ́n nwọ́n kã kún wòlĩ nlá, àti ẹni Ọlọ́run, tí ó ní agbára nlá àti àṣẹ tí Ọlọ́run fi fún un. Ẹ sì kíyèsĩ, Léhì arákùnrin rẹ̀ kò gbẹ́hìn rárá níti ohun tíi ṣe ti òdodo. Báyĩ ni ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn Nífáì tún bẹ̀rẹ̀sí ṣe rere lórí ilẹ̀ nã, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí tún àwọn ibi ahoro nwọn kọ́, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pọ̀ síi tí nwọn sì ntànkálẹ̀, àní títí nwọn fi borí gbogbo ilẹ̀ nã, ní apã ríwá, áti ní apá gũsù, láti òkun apá ìwọ̀-oòrùn títí dé òkun apá ìlà-oòrùn. Ó sì ṣe tí ọdún kẹrìndínlọ́gọ́rin parí ní àlãfíà. Ọdún kẹtàdínlọ́gọ́rin sì bẹ̀rẹ̀ ní àlãfíà; ìjọ nã sì tànkálẹ̀ jákè-jádò orí ilẹ̀nã gbogbo; èyítí ó pọ̀ jù nínú àwọn ènìyàn nã, nínú àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì, ni ó sì wà nínú ìjọ nã; nwọ́n sì ní àlãfíà èyítí ó pọ̀ púpọ̀ ní ilẹ̀ nã; báyĩ sì ni ọdún kẹtàdínlọ́gọ́rin parí. Àti pẹ̀lú nwọn ni àlãfíà nínú ọdún kejìdínlọ́gọ́rin, àfi fún asọ̀ díẹ̀díẹ̀ tí ó wà nípa àwọn ẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ èyítí àwọn wòlĩ ti fi lélẹ̀. Àti nínú ọdún kọkàndínlọ́gọ́rin ni asọ̀ púpọ̀ bẹ̀rẹ̀sí wà. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí Nífáì àti Léhì, àti púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin nwọn tí ó mọ̀ nípa àwọn ẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ nwọn, nítorípé nwọ́n ngba ìfihàn púpọ̀púpọ̀ lójojúmọ́, nítorínã nwọ́n sì nwãsù sí àwọn ènìyàn nã, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi òpin sí àwọn asọ̀ nwọn nínú ọdún kannã. Ó sì ṣe nínú ọgọ́rin ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, àwọn olùyapa-kúrò lára àwọn ará Nífáì kan, tí nwọ́n ti lọ bá àwọn ará Lámánì ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, tí nwọ́n sì ti fún ara nwọn ní orúkọ àwọn ará Lámánì, àti pẹ̀lú àwọn kan tí irú ọmọ àwọn ará Lámánì nítorípé nwọ́n ru nwọn sókè ní ìbínú, àtí pé àwọn olùyapa-kúrò nnì ru nwọn sókè ní ìbínú, nítorínã nwọ́n bẹ̀rẹ̀ ogun jíjà pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn. Nwọ́n sì nṣe ìpànìyàn àti ìkógun; nwọ́n ó sì sá padà sínú àwọn òkè gíga, àti sínú aginjù àti àwọn ibi kọ́lọ́fín, nwọn ó sì fi ara pamọ́ tí nwọn kò sì lè rí nwọn, nwọ́n sì nfikún ara nwọn lójojúmọ́, ní ìwọ̀n ìgbàtí àwọn olùyapa-kúrò wà tí nwọn ntọ̀ nwọ́n lọ. Àti báyĩ láìpẹ́, bẹ̃ni, àní lãrín ìwọ̀n ọdún díẹ̀, nwọ́n di ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà tí ó tóbi púpọ̀; nwọ́n sì ṣe àwárí gbogbo àwọn ìmọ̀ òkùnkùn Gádíátónì; báyĩ ni nwọ́n sì di ọlọ́ṣà Gádíátónì. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, àwọn ọlọ́ṣà yĩ ṣe ohun ibi púpọ̀, bẹ̃ni, àní ìparun púpọ̀ lãrín àwọn ènìyàn Nífáì, àti lãrín àwọn ènìyàn ará Lámánì pẹ̀lú. Ó sì ṣe tí ó di ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe láti fi òpin sí iṣẹ́ ìparun yìi; nítorínã nwọ́n rán ẹgbẹ́ ọmọ ogun alágbára ọkùnrin sí ínú aginjù àti sí ínú àwọn òkè gíga nã láti wá àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà nã rí, àti láti pa nwọ́n run. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ó sì ṣe nínú ọdún kannã nwọ́n lé nwọn padà àní sínú ilẹ̀ nwọn. Báyĩ sì ni ọgọ́rin ọdún parí nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì. Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kọkànlélọ́gọ́rin nwọ́n sì tún kọjá lọ láti kọlu àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà yĩ, nwọ́n sì pa púpọ̀; àwọn nã sì fi ara bá àdánú tí ó pọ̀. Ó sì tún di dandan fún nwọn láti padà kúrò nínú aginjù nã àti kúrò nínú àwọn òkè gíga nã lọ sínú ilẹ̀ nwọn, nítorí púpọ̀ tí àwọn ọlọ́ṣà nã pọ̀ tí nwọ́n ti gba inú gbogbo àwọn òkè gíga àti aginjù nã tán. Ó sì ṣe tí ọdún yĩ parí báyĩ. Àwọn ọlọ́ṣà nã sì npọ̀ síi nwọ́n sì ntẹ̀síwájú nínú agbára, tóbẹ̃ tí nwọn kò ka gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì sí, àti ti àwọn ará Lámánì pẹ̀lú; nwọ́n sì mú kí ẹ̀rù nlá ó bá àwọn ènìyàn nã lórí gbogbo ilẹ̀ nã. Bẹ̃ni, nítorítí nwọ́n bẹ àwọn ibi púpọ̀ wò lórí ilẹ̀ nã, nwọ́n sì ṣe ìparun nlá níbẹ̀; bẹ̃ni, nwọ́n pa ọ̀pọ̀lọpọ̀, nwọ́n sì mú àwọn yókù lọ ní ìgbẹ̀kùn sínú aginjù, bẹ̃ni, àti pãpã àwọn obìnrin nwọn àti àwọn ọmọ nwọn. Nísisìyí ohun búburú nlá yĩ, èyítí ó dé bá àwọn ènìyàn nã nítorí ìwà àìṣedẽdé nwọn, sì tún ta nwọ́n jí sí ìrántí Olúwa Ọlọ́run nwọn. Báyĩ sì ni ọdún kọkànlélọ́gọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ parí. Àti nínú ọdún kejìlélọ́gọ́rin nwọ́n tún bẹ̀rẹ̀sí gbàgbé Olúwa Ọlọ́run nwọn. Àti nínú ọdún kẹtàlélọ́gọ́rin nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí tẹ̀síwájú nínú àìṣedẽdé. Àti nínú ọdún kẹrìnlélọ́gọ́rin nwọ́n kò tún ọ̀nà nwọn ṣe. Ó sì ṣe nínú ọdún karundinlãdọrun nwọ́n sí nní agbára síi nínú ìwà ìgbéraga, àti nínú ìwà búburú nwọn; báyĩ nwọ́n sì nmúrasílẹ̀ fún ìparun. Báyĩ sì ni ọdún karundinlãdọrun parí. 12 Àwọn ènìyàn a máa ṣe aláìfẹsẹ̀ mulẹ̀ nwọ́n sì jẹ́ aláìgbọ́n nwọ́n sì yára láti ṣe búburú—Olúwa a máa bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí—A fi ipò asán àwọn ènìyàn wé agbára Ọlọ́run—Ní ọjọ́ ìdájọ́, àwọn ènìyàn yíò rí ayé àìnípẹ̀kun gbà tàbí ìdálẹ́bi ayérayé. Ní ìwọ̀n ọdún 6 kí a tó bí Olúwa wa. Àti báyĩ àwa lè ríi bí àwọn ọmọ ènìyàn ti jẹ́ aláìṣọ́tọ́ tó, àti bí ọkàn nwọn ti wà láìdúróṣinṣin tó; bẹ̃ni àwa lè ríi pé Olúwa nínú dídára rẹ̀ nlá, tí kò lópin a máa bùkún fun, a sì máa mú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ nwọn lé e ṣe dẽdé. Bẹ̃ni, àwa sì lè ríi ní àkókò nã gan nígbàtí ó bá bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̃ni, nínú èrè oko nwọn, àwọn ọ̀wọ́ àti agbo ẹran nwọn, àti nínú wúrà àti nínú fàdákà àti nínú onírurú ohun olówó-iyebíye lóríṣiríṣi; tí ó sì dá ẹ̀mí nwọn sí, tí ó sì gba nwọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọ́n; tí ó sì mú ọkàn àwọn ọ̀tà nwọn rọ̀ tí nwọn kò sì gbógun tì nwọ́n; bẹ̃ni, àti ní kúkúrú, tí ó ṣe ohun gbogbo fún àlãfíà àti inúdídùn àwọn ènìyàn rẹ̀; bẹ̃ni, nígbànã ni nwọn yíò sé ọkàn nwọn le, tí nwọ́n sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run nwọn, tí nwọn yíò sì tẹ Ẹmí Mímọ́ nnì mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ nwọn—bẹ̃ni, èyí sì rí bẹ̃ nítorítí nwọ́n wà ní ípò ìdẹ̀ra, àti nítorí ọrọ̀ púpọ̀ tí nwọ́n ní. Báyĩ ni àwa sì rí i pé bí kò ṣe pé Olúwa bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú, bẹ̃ni, bí kò ṣe pé ó bẹ̀ nwọ́n wò pẹ̀lú ikú àti ẹ̀rù, àti pẹ̀lú ìyàn, àti pẹ̀lú onírurú àjàkálẹ̀-àrùn, nwọn kò ní rántí rẹ̀. A! báwo ni nwọ́n ti jẹ́ aláìgbọ́n tó, àti olùgbéraga, àti olùṣebúburú, àti ẹlẹmi èṣù, àti báwo ni nwọ́n ti yára tó láti ṣe àìṣedẽdé, àti báwo ni àwọn ọmọ ènìyàn, ti lọ́ra láti ṣe èyítí ó dára tó; bẹ̃ni, báwo ni nwọ́n ti yára tó láti tẹtisi ẹni búburú nnì, àti láti kó ọkàn nwọn lé àwọn ohun asán ayé! Bẹ̃ni, báwo ni nwọ́n ti yára tó láti gbé ọkàn sókè nínú ìgbéraga; bẹ̃ni, báwo ni nwọ́n ti yára làtilérí tó átí láti hu onírurú ìwà àìṣedẽdé; àti báwo ni nwọ́n ti lọ́ra tó láti rántí Olúwa Ọlọ́run nwọn, àti láti fetísí ìmọ̀ràn rẹ̀, bẹ̃ni, báwo ni nwọ́n ti lọ́ra tó láti rìn ní ọ́nà ọgbọ́n! Ẹ kíyèsĩ, nwọn kò ní ìfẹ́ pé kí Olúwa Ọlọ́run nwọn, ẹnití ó dá nwọn, kí ó jọba lórí nwọn; l’áìṣírò ire àti ãnú rẹ̀ pọ̀ sí nwọn, nwọ́n ka ìmọ̀ràn rẹ̀ kún asán, nwọn kò sì fẹ́ kí ó ṣe amọ̀nà nwọn. A! báwo ni ipò asán àwọn ọmọ ènìyàn ti tóbi tó, bẹ̃ni, àní nwọn kò dára tó erùpẹ̀ ilẹ̀. Nítorí kíyèsĩ, erùpẹ̀ ilẹ̀ a máa lọ sihin àti sọhun, a sì fọ́nká, ní ìgbọ́ran sí àṣẹ Ọlọ́run wa ayérayé tí ó tóbi. Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ ó sọ̀rọ̀ àwọn òkè kékèké àti àwọn òkè gíga wá rìrì nwọ́n sì mì tìtì. Nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ni nwọ́n fọ́ sí wẹ́wẹ́, nwọ́n sì di pẹ̀tẹ́lẹ̀, bẹ̃ni àní bí àfonífojì. Bẹ̃ni, nípa agbára ohùn rẹ ní gbogbo ayé ni tìtì. Bẹ̃ni, nípa agbára ohun rẹ, ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé mì tìtì, àní tí ó fi dé agbedeméjì rẹ̀. Bẹ̃ni, bí ó bá sì sọ fún ayé wípé—Ṣí ipò padà—yíò ṣí ípò padà. Bẹ̃ni, bí o bá sọ fún ayé wípé— Ìwọ yíò sún padàsẹ́hìn, kí ó lè mú kí ojúmọ́ kí ó gùn síi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí—ó sì rí bẹ̃; Àti báyĩ, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ayé sún padà sẹ́hìn, lójú ọmọ ènìyàn ó sì dàbí èyítí oòrùn dúró lójúkan; bẹ̃ni, ẹ sì kíyèsĩ, èyí sì rí bẹ̃; nítorítí dájúdájú ayé ni ó ṣípòpadà kĩ sĩ ṣe oòrùn. Ẹ sì kíyèsĩ, pẹ̀lú, bí ó bá sọ fún àwọn omi inú ibú nlá wípé—Ẹ di gbígbẹ—ó rí bẹ̃. Ẹ kíyèsĩ, bí ó bá sọ fún òkè gíga yĩ—Dìde, kí ó sì bọ́ sí ìhín kí o wó lu ìlú-nlá nnì, kí ó sì di bíbòmọ́lẹ̀ pátápátá—ẹ kíyèsĩ ó rí bẹ̃. Ẹ sì kíyèsĩ, bí ẹnìkan bá fi ìṣúra pamọ́ sínú ilẹ̀, tí Olúwa sì wípé: Kí ó di ìfibú, nítorí ìwà àìṣedẽdé ẹnití ó fi pamọ́—ẹ kíyèsĩ, yíò di ìfíbú. Bí Olúwa bá sì wípé—Kí ìwọ ó di ìfibú, kí ẹnìkẹ́ni ó má lè rí ọ mọ́ láti àkokò yĩ lọ àti títí láéláé—ẹ kíyèsĩ, ẹnìkẹ́ni kò lè ríi mọ́ láti àkokò yĩ lọ àti títí láéláé. Ẹ kíyèsĩ, bí Olúwa yíò bá wí fún ẹnìkan pé—Nítorí àwọn àìṣedẽdé rẹ, ìwọ yíò di ìfibú títí láéláé—yíò rí bẹ̃. Bí Olúwa yíò bá sí wípé— Nítorí àwọn àìṣedẽdé rẹ̀ ìwọ yíò di kíké kúrò níwájú mi—yíò sì mú kí ó rí bẹ̃. Ègbé sì ni fún ẹnití yíò sọ eleyĩ fún, nítorítí yíò rí bẹ̃ fún ẹnití ó bá ṣe àìṣedẽdé, a kò sì lè gbã là; nítorínã, fún ìdí èyí, láti lè gba ènìàyn là, ni a ti sọ nípa ìrònúpìwàdà. Nítorínã, alábùkún-fún ni àwọn tí yíò ronúpìwàdà tí nwọn yíò sì tẹtisi ohùn Olúwa Ọlọ́run nwọn; nítorítí àwọn yĩ ni a ó gbàlà. Kí Ọlọ́run kí ó jẹ́, nínú pípé rẹ̀, kí a mú àwọn ènìyàn sí ìrònúpìwàdà àti iṣẹ́ rere, kí a lè fún nwọn ní ọ́re-ọ̀fẹ́ kún ọ́re-ọ̀fẹ́, gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ nwọn. Èmi sì fẹ́ kí gbogbo ènìyàn di gbìgbàlà. Ṣùgbọ́n a ríi kà pé ní ọjọ́ ìkẹhìn nlá nnì àwọn kanwà tí a ó lé jáde, bẹ̃ni, tí a ó lé kúrò ní iwájú Olúwa; Bẹ̃ni, àwọn ni a ó yàn sí ipò ìrora tí kò lópin, báyĩ sì ni nwọn yíò mú ọ̀rọ̀ nã ṣẹ tí ó wípé: Àwọn tí ó ti ṣe rere yíò ní ìyè àìlópin; àwọn tí ó sì ti ṣe búburú yíò ní ìdálẹ́bi àìlópin. Báyĩ sì ni ó rí. Àmín. Èyí ni ìsọtẹ́lẹ̀ Sámúẹ́lì, ará Lámánì, sí àwọn ará Nífáì. Èyítí a kọ sí àwọn orí 13 títí ó fi dé 15 ní àkópọ̀. 13 Sámúẹ́lì ẹ̀yà Lámánì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun àwọn ará Nífáì àfi bí nwọ́n bá ronúpìwàdà—Àwọn àti ọrọ̀ nwọn ni a fi bú—Nwọ́n kọ àwọn wòlĩ tí nwọ́n sì sọ nwọ́n ní okuta, àwọn ẹ̀míkẹ́mi yí nwọn kákiri, nwọ́n sì ńdunnú kiri nínú ìwà àìṣedẽdé. Ní ìwọ̀n ọdún 6 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe nínú ọdún kẹrìndínlãdọ́run, àwọn ará Nífáì sì wà nínú ìwà búburú, bẹ̃ni, nínú ìwà búburú tí ó pọ̀, nígbàtí àwọn ará Lámánì sì tẹramọ́ pípa òfin Ọlọ́run mọ́, ní ìbámu pẹ̀lú òfin Mósè. Ó sì ṣe nínú ọdún yìi tí ẹnìkan wà tí à npè orúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì, ẹ̀yà Lámánì, ẹnití ó wá sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ó sì bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí àwọn ènìyàn nã. Ó sì ṣe tí ó wãsù ìronúpìwàdà fún ọjọ́ pípẹ́, sí àwọn ènìyàn nã, nwọ́n sì lée jáde, ó sì ṣetán láti padà sí ilẹ̀ tirẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ohùn Olúwa tọ̣́ wá, pé kí ó tún padà lọ, kí ó sì sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn nã nípa ohunkóhun tí ó bá wá sí ọkàn rẹ̀. Ó sì ṣe tí nwọn kò jẹ́ kí ó wọ inú ìlú nã; nítorínã ó lọ ó sì dúró lórí ògiri rẹ̀, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì kígbe pẹ̀lú ohùn rara, ó sì sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn nã nípa àwọn ohunkóhun tí Olúwa fi sí ọkàn rẹ̀. Ó sì wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, èmi, Sámúẹ́lì, ará Lámánì, ni ó nsọ ọ̀rọ̀ Olúwa èyítí ó fi sí ọkàn mi; ẹ sì kíyèsĩ ó ti fií sí ọkàn mi láti sọọ́ fún àwọn ènìyàn yĩ pé àìṣègbè idà yíò wà ní gbígbé sókè lórí àwọn ènìyàn yĩ; irínwó ọdún kò sì ní kọjá kí àìṣègbè idà ó tó kọlũ àwọn ènìyàn yĩ. Bẹ̃ni, ìparun tí ó tóbi ndúró de àwọn ènìyàn yĩ, dájúdájú ni ó nbọ̀ lórí àwọn ènìyàn yĩ, kò sì sí ohun tí ó lè gbà nwọ́n bíkòṣe ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì Olúwa, tí nbọ̀ dájúdájú sínú ayé yĩ, tí yíò sì faradà ohun púpọ̀ àti tí a ó pa fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Ẹ kíyèsĩ, ángẹ́lì Olúwa kan ti sọ ọ́ fún mi, ó sì mú ìròhìn ayọ̀ sínú ọkàn mi. Ẹ sì kíyèsĩ, a rán mi láti sọọ́ fún nyín pẹ̀lú, kí ẹ̀yin ó lè ní ìròhìn ayọ̀ ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ ẹ̀yin kò gbà mí. Nítorínã, báyĩ ni Olúwa wí: Nítorí líle ọkàn àwọn ènìyàn ará Nífáì, bíkòṣepé nwọ́n ronúpìwàdà, èmi yíò mú ọ̀rọ̀ mi kúrò lọ́dọ̀ nwọn, èmi yíò sì mú Ẹ̀mí mi kúrò lọ́dọ̀ nwọn, èmi kò sì ní gbà nwọ́n lãyè mọ́, èmi yíò sì yí ọkàn àwọn arákùnrin nwọn takò nwọ́n. Irínwó ọdún kò sì ní kọjá kí èmi ó tó mú kí nwọn ó kọlũnwọ́n; bẹ̃ni, èmi yíò bẹ̀ nwọ́n wò pẹ̀lú idà, àti pẹ̀lú ìyàn àti pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn. Bẹ̃ni, èmí yíò bẹ̀ nwọ́n wò nínú gbìgbóná ìbínú mi, nínú àwọn ìran kẹrin àwọn ọ̀tá nyín, yíò sì wà lãyè, láti rí ìparun nyín pátápátá; èyí yíò sì rí bẹ̃ bíkòṣepé ẹ̀yin ronúpìwàdà, ni Olúwa wí; àwọn ìran kẹrin nnì yíò sì mú ìparun bá nyín. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà kí ẹ sì yí padà sí ọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín èmi yíò mú ìbínú mi kúrò, ni Olúwa wí; bẹ̃ni, báyĩ ni Olúwa wí, alábùkún-fún ni àwọn tí yíò ronúpìwàdà tí nwọn yíò sì yí padà sí ọ́dọ̀ mi, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹnití kò ronúpìwàdà. Bẹ̃ni, ègbé ni fún ìlú-nlá Sarahẹ́múlà títóbi yĩ; nítorítí ẹ kíyèsĩ, nítorí àwọn tí ó jẹ́ olódodo ni a ṣe gbà á là; bẹ̃ni, ègbé ni fún ìlú-nlá títóbí yĩ, nítorítí mo wòye, ni Olúwa wí, pé púpọ̀ nínú nwọn ni ó wà, bẹ̃ni, àní èyítí ó jù nínú àwọn ará ìlú-nlá títóbí yĩ, tí yíò sé àyà nwọn le sí mi, ni Olúwa wí. Ṣùgbọ́n alábùkún-fún ni àwọn tí yíò ronúpìwàdà, nítorítí àwọn ni èmi yíò dá sí. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, bí kò bá ṣe nítorí àwọn olódodo tí ó wà nínú ìlú-nlá títóbí yĩ, ẹ kíyèsĩ, èmi ìbá mú kí iná bọ́ láti ọ̀run kí ó sì pã run. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, nítorí àwọn olódodo ni a ṣe dáa sí. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àkokò nã dé tán, ni Olúwa wí, nígbàtí ẹ̀yin yíò lé àwọn olódodo kúrò lãrín yín, nígbànã ní ẹ̀yin yíò ṣetán fún ìparun; bẹ̃ni, ègbé ni fún ìlú-nlá títóbi yĩ, nítorí ìwà búburú àti ìwà ẽrí tí ó wà nínú rẹ̀. Bẹ̃ni, ègbé sì ní fún ìlú-nlá Gídéónì, nítorí ìwà búburú àti ìwà ẽrí tí ó wà nínú rẹ̀. Bẹ̃ni, ègbé sì ni fún gbogbo àwọn ìlú-nlá tí ó wà ní ilẹ̀ àyíká, èyítí àwọn ará Nífáì ní ní ìní, nítorí ìwà búburú àti ìwà ẽrí tí ó wà nínú nwọn. Ẹ sì kíyèsĩ, a ó fi ilẹ̀ nã bú, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, nítorí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ nã, bẹ̃ni, nítorí ìwà búburú àti ìwà ẽrí nwọn. Yíò sì ṣe, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, bẹ̃ni, Ọlọ́run wa alágbára àti òlótítọ́, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá kó ìṣúra pamọ́ lórí ilẹ̀ ayé kò ní rí nwọn mọ́, nítorí ègún nlá tí ó wà lórí ilẹ̀ nã, àfi bí ó bá jẹ́ olódodo ènìyàn tí yíò sì fi pamọ́ nínú Olúwa. Nítorítí èmi fẹ́, ni Olúwa wí, pé kí nwọ́n fi ìṣúra nwọn pamọ́ nínú mi; ègbé sì ni fún àwọn tí kò bá fi ìṣùra nwọn pamọ́ sínú mi; nítorítí kò sí ẹnití nfi ìṣúra rẹ̀ pamọ́ nínú mi bíkòṣe olódodo ènìyàn; ẹnití kò bá sì fi ìṣúra rẹ̀ pamọ́ sínú mi, ègbé ni fún un, àti ìṣúra nã, kò sì sí èyítí yíò rã padà nítorí ègún tí ó wà lórí ilẹ̀ nã. Ọjọ́ nã sì nbọ̀ tí nwọn yíò fi ìṣura nwọn pamọ́, nítorípé nwọ́n ti kó ọkàn nwọn lé ọrọ̀; àti nítorípé nwọn ti kó ọkàn nwọn lé ọrọ̀ nwọn, tí nwọn yíò sì fi ìṣúra nwọn pamọ́ nígbàtí nwọ́n bá sálọ kúrò níwájú àwọn ọ̀tá nwọn; nítorípé nwọn kọ̀ láti fi nwọ́n pamọ́ nínú mi, ègbé ni fún nwọn àti àwọn ìṣúra nwọn; ní ọjọ́ nã ni a ó sì kọlũ nwọ́n, ni Olúwa wí. Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ènìyàn ìlú-nlá títóbi yĩ, kí ẹ sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi; bẹ̃ni kí ẹ sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ tí Olúwa wí; nítorí ẹ kíyèsĩ, ó wípé a fi yín bú nítorí ọrọ̀ nyín, àti pẹ̀lú pé a ti fi ọrọ̀ nyín bú nítori ẹ̀yin tí kó ọkàn nyín le nwọn, tí ẹ̀yin kò sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹni nã tí ó fi nwọn fún nyín. Ẹ̀yin kò rántí Olúwa Ọlọ́run nyín nínú ohun tí ó ti fi bùkún nyín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin a máa rántí ọrọ̀ nyín ní gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run nyín fún nwọ́n; bẹ̃ni, ọkàn nyín kò fà sí ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n nwọn gbé sókè pẹ̀lú ìgbéraga tí ó tóbi, sí lílérí àti sí ìbínú líle, owú-jíjẹ, ìjà, àrakàn, inúnibíni, ìpànìyàn, àti onírurú ìwà àìṣedẽdé. Ní ìdí èyí ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ègún ó wá sí órí ilẹ̀ nã, àti sí órí àwọn ọrọ̀ nyín pẹ̀lú, èyí sì rí bẹ̃ nítorí ìwà àìṣedẽdé nyín. Bẹ̃ni, ègbé ni fún àwọn ènìyàn yĩ, nítorí àkokò yĩ tí ó ti dé, tí ẹ̀yin lé wòlĩ jáde, tí ẹ sì nfi nwọ́n ṣe ẹlẹ́yà, tí ẹ sì nsọ nwọ́n ní okuta, tí ẹ sì pa nwọn, tí ẹ sì hu onírurú ìwà àìṣedẽdé sí nwọn, àní bí àwọn ará ìgbà nnì ti ṣe. Àti nísisìyí nígbàtí ẹ̀yin bá nsọ̀rọ̀, ẹ̀yin nsọ wípé: Bí àwa bá wà láyé ní ìgbà àwọn bàbá nlá wa, àwa kì bá ti pa àwọn wòlĩ nnì; àwa kì bá ti sọ nwọ́n ní okuta, kí a sì lé nwọn jáde. Ẹ kíyèsĩ ẹ̀yin burú jù nwọ́n lọ; nítorítí bí Olúwa ti wà lãyè, bí wòlĩ bá wá sí ãrín nyín tí ó sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa pẹ̀lú nyín, tí ó jẹ́rĩ sí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedẽdé nyín, ẹ̀yin yíò bínú síi, ẹ̀yin yíò sì lée jáde ẹ̀yin yíò sì wá onírurú ọ̀nà láti pã run; bẹ̃ni, ẹ̀yin yíò wípé wòlĩ èké ni í ṣe, àti pé ẹlẹ́ṣẹ̀ nií ṣe, àti ti èṣù, nítorípé ó jẹ́rĩ pé iṣẹ́ ọwọ́ nyín jẹ́ èyítí ó burú. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, bí ẹnìkan bá wá sí ãrín nyín tí ó sì wípé: Ẹ ṣe eleyĩ, pé kò sì sí àìṣedẽdé; ẹ ṣe tọ̀hún pé ẹ̀yin kò sì ní jìyà; bẹ̃ni tí òun wípé: Ẹ máa rìn nínú ìgbéraga ọkàn nyín; bẹ̃ni, ẹ máa rìn nínú ìgbéraga ojú nyín, kí ẹ sì máa ṣe ohunkóhun tí ọkàn nyín bá fẹ́—bí ẹnìkan bá sì wá sí ãrin nyín tí ó sọ èyí, ẹ̀yin yíò gbã, ẹ ó sì sọ wípé wòlĩ ni. Bẹ̃ni, ẹ̀yin yíò gbée ga, ẹ̀yin yíò sì fún un nínú ohun ìní nyín; ẹ̀yin yíò fún un nínú wúrà nyín, àti nínú fàdákà nyín, ẹ̀yin yíò sì wọ ẹ̀wù olówó-iyebíye síi lọ́rùn; àti nítorípé ó nsọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn pẹ̀lú nyín, tí òun sì sọ pé dáradára ni ohun gbogbo, nígbànã ni ẹ̀yin kò ní rí ohun tí ó burú nínú rẹ̀. A! ẹ̀yin ènìyàn ìkà àti ìran aláìṣọ́tọ́ yĩ; ẹ̀yin aláìgbọ́ran àti ọlọ́rùn líle ènìyàn yĩ, báwo ni yíò ti pẹ́ tó ti ẹ̀yin rò pé Olúwa yíò gbà fún nyín? Bẹ̃ni, báwo ni yíò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin yíò jẹ́ kí aṣiwèrè àti afọ́jú ènìyàn ó darí nyín? Bẹ̃ni, báwo ni yíò ti pẹ́ tó ti ẹ̀yin yíò yan òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀? Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, ìbínú Olúwa ti dé tán lórí nyín; ẹ kíyèsĩ, ó ti fi ilẹ̀ nã bú nítorí àìṣedẽdé nyín. Ẹ sì kíyèsĩ, àkokò nã nbọ̀ tí yíò fi ọ̀rọ̀ nyín bú, tí nwọn yíò ma yọ́ bọ́rọ́, tí ẹ̀yin kò ní lè dì nwọ́n mú; ní ọjọ́ àìní nyín ẹ̀yin kò sì ní lè mú nwọn dání. Ní ọjọ́ àìní nyín sì ni ẹ̀yin yíò ké pe Olúwa; lásán ni ẹ̀yin yíò sì kígbe, nítorí ìsọdáhórò nyínti dé sí órí nyín, ìparun nyín sì ti wà dájúdájú; nígbànã ni ẹ̀yin yíò sọkún tí ẹ̀yin yíò sì ké ní ọjọ́ nã, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí. Nígbànã ni ẹ̀yin yíò pohùnréré ẹkún, tí ẹ ó sì wípé: A! èmi ìbá ti ronúpìwàdà, tí èmi ìbá má sì pa àwọn wòlĩ nì, tí mo sọ nwọ́n ní okuta, tí mo sì lé nwọn jáde. Bẹ̃ni ní ọjọ́ nã ẹ̀yin yíò wípé: Àwa ìbá ti rántí Olúwa Ọlọ́run wa ní ọjọ́ tí ó fún wa ní ọrọ̀, nwọn kì bá sì ti má a yọ́ bọ́rọ́ tí àwa sì pàdánù nwọn; nítorítí ẹ kíyèsĩ, ọrọ̀ wa ti lọ kúrò lọ́dọ̀ wa. Ẹ kíyèsĩ, àwa fi ohun èlò kan sí ibí nígbàtí ó sì di ọjọ́ kejì ó ti lọ; ẹ sì kíyèsĩ, nwọ́n mú àwọn idà wa kúrò lọ́dọ̀ wa ní ọjọ́ tí àwa nwá nwọn láti jagun. Bẹ̃ni, àwa ti fi ìṣúra wa pamọ́ nwọ́n sì ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ wá, nítorí ègún orí ilẹ̀ nã. A! àwa ìbá ti ronúpìwàdà ní ọjọ́ nã ti ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ wá wá; nítorí ẹ kíyèsĩ a ti fi ilẹ̀ nã bú, ohun gbogbo sì ti di yíyọ̀ bọ̀rọ̀, àwa kò sì lè dì nwọ́n mú. Ẹ kíyèsĩ, àwọn ẹmikẹmi ni ó yí wa ká, bẹ̃ni, àwọn ángẹ́lì ẹni nã tí ó ti wá ọ̀nà láti pa ọkàn wa run yí wa ká. Ẹ kíyèsĩ, àwọn àìṣedẽdé wa tóbi. A! Olúwa, ìwọ kò ha lè mú ìbínú rẹ̀ kúrò lórí wa bí? Báyĩ sì ní èdè nyín yíò rí ní àwọn ọjọ́ nã. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ọjọ́ ìdánwò nyín ti parí; ẹ̀yin tí foni-doni lórí ọjọ́ ìgbàlà nyín títí ó fi di èyítí ó pẹ́ ju títí ayé àìnípẹ̀kun, ìparun nyín sì wà dájúdájú; bẹ̃ni, nítorítí ẹ̀yin ti fi gbogbo ọjọ́ ayé nyín wa èyítí ẹ̀yin kò lè rí gbà kiri; ẹ̀yin sì nlépa àlãfíà nínú híhu ìwà àìṣedẽdé, ohun èyítí ó tako ìwà òdodo nnì èyítí nbẹ nínú Ọba Ayérayé wa. A! ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ nã, ẹ̀yin ìbá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi! Èmi sì gbàdúrà kí ìbínú Olúwa kúrò lórí nyín, àti kí ẹ̀yin ó ronúpìwàdà kí a sì gbà nyín là. 14 Sámúẹ́lì sọ ìsọtẹ́lẹ̀ pé ìmọ́lẹ̀ yíò wà ní álẹ́ àti pé ìràwọ̀ titun yíò wà ní àkokò bíbí Krístì—Krístì ṣe ìràpadà fún àwọn ènìyàn kúrò lọ́wọ́ ikú ara àti ti ẹ̀mí—Àwọn àmì ikú rẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́ta tí òkùnkùn ṣú bo ilẹ̀, fífọ́ àwọn òkè, ati ìrúkèrúdò nínú ayé. Ní ìwọ̀n ọdún 6 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Sámúẹ́lì, ará Lámánì nnì, sọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun púpọ̀ síi tí a kò lè kọ sílẹ̀. Ẹ sì kíyèsĩ, ó wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ èmi yíò fún un nyín ní àmì kan; nítorítí ọdún marun sì nbọ̀wá, ẹ sì kíyèsĩ, nígbànã ni Ọmọ Ọlọ́run yíò wá láti ra gbogbo àwọn tí yíò gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́ padà. Ẹ sì kíyèsĩ, èyí ni èmi yíò fún nyín gẹ́gẹ́bí àmì tí yíò sẹ́ nígbàtí ó bá dé; nítorí kíyèsĩ, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbí yíò wà lọ́run tóbẹ̃ tí kò ní sí òkùnkùn ní òru ọjọ́ tí ó ṣãjú ọjọ́ bíbọ̀ rẹ̀, tóbẹ̃ tí yíò dàbí ọ̀sán lójú àwọn ènìyàn. Nítorínã a ó ní ọ̀sán kan àti alẹ́ kan àti ọ̀sán kan, bí èyítí ó jẹ́ ọjọ́ kan tí kò sì sí òru; èyí ni yíò sì wà gẹ́gẹ́bí àmì fún nyín; nítorítí ẹ̀yin yíò mọ̀ nípa títàn oòrùn àti wíwọ̀ rẹ̀; nítorínã nwọn yíò mọ̀ dájúdájú pé ọ̀sán méjì àti òru kan yíò wà; bíótilẹ̀ríbẹ̃ òrukò ní ṣókùnkùn; yíò sì jẹ́ òru ọjọ́ tí a o bĩ. Ẹ sì kíyèsĩ, ìràwọ̀ tuntun kan yíò yọ, èyítí ẹ̀yin kò rí irú rẹ̀ rí; èyí pẹ̀lú yíò sì jẹ́ àmì fún nyín. Ẹ kíyèsĩ kò tán síbẹ̀, àwọn ohun àmì àti ìyanu púpọ̀ yíò wà lọ́run. Yíò sì ṣe tí ẹnu yíò yà nyín, tóbẹ̃ tí ẹ̀yin yíò ṣubú lulẹ̀. Yíò sì ṣe tí ẹnìkẹ́ni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run nã gbọ, òun nã ni yíò ní ìyè títí ayé. Ẹ sì kíyèsĩ, báyĩ ni Olúwa ti pãláṣẹ fún mi, láti ọwọ́ ángẹ́lì rẹ̀, pé kí èmi wá láti sọ ohun yĩ fún nyín; bẹ̃ni, ó ti pàṣẹ pé kí èmi ó sọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun wọ̀nyí fún nyín; bẹ̃ni, ó ti sọ fún mi pé: Kígbe sí àwọn ènìyàn yĩ, ẹ ronúpìwàdà kí ẹ sì tún ọ̀nà Olúwa ṣe. Àti nísisìyí, nítorípé ará Lámánì ni èmi í ṣe, tí mo sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti pa láṣẹ fún mi fún nyín, àti nítorípé ó nira fún nyín ní ṣíṣe, ẹ̀yin nbínú sí mi ẹ sì nlépa láti pa mí run, ẹ sì ti lé mi jáde kúrò lãrín nyín. Ẹ̀yin yíò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, nítorítí, nítorí ìdí èyí ni èmi wá sí órí àwọn ògiri ìlú-nlá yĩ, kí ẹ̀yin kí ó lè gbọ́ kí ẹ sì mọ̀ nípa ìdájọ́ Ọlọ́run èyítí ó ndúró dè nyín nítorí àwọn ìwà àìṣedẽdé nyín, àti kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ nípa ọ̀nà ìrònúpìwàdà; Àti pẹ̀lú kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ nípa bíbọ̀ Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, Bàbá ọ̀run òun ayé, Ẹlẹ́dã ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ wá; àti kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ nípa àwọn àmì nípa bíbọ̀ rẹ̀, láti lè mú kí ẹ̀yin ó gbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀. Bí ẹ̀yin bá sì gbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀ ẹ̀yin yíò ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nyín, pé lọ́nà yĩ ẹ̀yin yíò gba ìdáríjì lórí nwọn nípasẹ̀ ìdáláre. Ẹ sì kíyèsĩ, àmì míràn ni èmi yíò tún fún nyín, bẹ̃ni àmì tí ikú rẹ̀. Nítorí ẹ kíyèsĩ, dájúdájú ni yíò kú kí ìgbàlà lè wá; bẹ̃ni, ó níláti rí báyĩ, ó sì jẹ́ èyítí ó yẹ pé kí ó ku, láti mú àjínde òkú kọjá, pé báyĩ a ó mú ènìyàn wá sí iwájú Olúwa. Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, ikú yĩ mú àjínde wa, àti ìràpadà gbogbo ènìyàn kúrò nínú ikú àkọ́kọ́—ikú tí ẹ̀mi nnì; nítorítí gbogbo ènìyàn, nípa ìṣubú Ádámù ti di kíké kúrò níwájú Olúwa, wọn sì ti dàbí ẹnití ó kú, sí ohun ti ara àti ohun ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àjínde Krístì nṣe ìràpadà fún ènìyàn, bẹ̃ni, àní gbogbo ènìyàn, ó sì nmú nwọn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa. Bẹ̃ni, ó sì nmú ọ̀nà ìrònúpìwàdà wá, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà òun nã ni a kò ní ké lulẹ̀ kí a sì sọọ́ sínú iná nnì; ṣùgbọ́n ẹnìkẹ́ni tí kò bá ronúpìwàdà ni a ó ké lulẹ̀ tí a ó sì sọ ọ́ sínú iná nnì; níbẹ sì ni ikú ẹ̀mí yíò tún wá sí órí nwọn, bẹ̃ni, ikú kejì, nítorítí a ó tún ké nwọn kúrò ní ti ohun tí í ṣe ti ọ̀nà òdodo. Nítorínã ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà, ní ìbẹ̀rù pé bí ẹ̀yin ti mọ́ àwọn ohun yĩ tí ẹ kò sì ṣe nwọ́n ẹ̀yin yíò mú ara nyín wá sí abẹ́ ìdálẹ́bi, a ó sì mú nyín wá sínú ikú kejì yĩ. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, gẹ́gẹ́bí èmi ti wí fún nyín nípa àmì míràn,àmì ti ikú rẹ̀, ẹ kíyèsĩ, ní ọjọ́ nã tí yíò kú oòrun yíò ṣókùnkùn yíò sì kọ láti fún nyín ní ìmọ́lẹ̀ rẹ̀; àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú; kò sì ní sí ìmọ́lẹ̀ lójú ilẹ̀ yĩ, àní láti ìgbà tí yíò kú, fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta, títí dé ìgbà tí yíò jínde kúrò ní ipò òkú. Bẹ̃ni, ní ìgbà tí yíò jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ ãrá yíò san mọ̀nàmọ́na yio sì wà fún ìwọ̀n wákàtí púpọ̀, ayé yíò sì mì tìtì yíò sì gbọ̀n rìrì; àwọn àpáta tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, tí ó wà lókè àti lábẹ́ ilẹ́, èyítí ẹ̀yin mọ̀ ní àkokò yĩ pe nwọn le, tabi pé púpọ̀ nínú rẹ̀ jẹ́ èyítí ó le ní kíkópọ̀, ni yíò fọ́ sí wẹ́wẹ́. Bẹ̃ni, nwọ́n yíò là sí méjì, lẹhinnã nwọn ó sì wà ní ṣíṣán, àti ní fífọ́ sí wẹ́wẹ́ láti ìgbànã lọ, àti ní àkúfọ́ lórí ilẹ̀ gbogbo ayé, bẹ̃ni, lórí ilẹ̀ àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Ẹ sì kíyèsĩ, ìjì líle yíò wà, àwọn òkè gíga púpọ̀ ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀, bí àfonífojì, àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibití a sì npè ní àfonífojì ní àkokò yĩ ni yíò di òkè gíga, ti gíga nwọn sì jẹ́ púpọ̀. Àwọn ojú ọ̀nà òpópó púpọ̀ ni yíò sì fọ́ sí wẹ́wẹ́, àwọn ìlú-nlá púpọ̀ ní yíò sì di ahoro. Àwọn isà òkú púpọ̀ ni yíò sì ṣí sílẹ̀, tí nwọn yíò sì gbé púpọ̀ nínú àwọn òkú inú nwọn dìde; àwọn ènìyàn mímọ̀ púpọ̀ ni yíò sì farahàn sí àwọn ènìyàn púpọ̀. Ẹ sì kíyèsĩ, báyĩ sì ni ángẹ́lì nã ti bá mi sọ̀rọ̀; nítorítí ó sọ fún mi pé àrá yíò sán mọ̀nàmọ́na yio sì wà fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí. Ó sì sọ fún mi pé ní àkokò tí àra nã nsán tí mọ̀nàmọ́na sì nkọ, àti ìjì nã, pé àwọn ohun wọ̀nyí yíò rí bẹ̃, àti pé òkùnkùn yíò bò orí ilẹ̀ gbogbo ayé fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta. Ángẹ́lì nã sì wí fún mi pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò rí àwọn ohun tí ó ju eleyĩ, láti lè mú kí nwọn ó gbàgbọ́ pé àwọn àmì àti ohun ìyanu yĩ yíò ṣẹ lórí ilẹ̀ yĩ, láti lè mú àìgbàgbọ́ kúrò lãrín àwọn ọmọ ènìyàn— Èyí sì rí bẹ̃ láti lè mú kí ẹnìkẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ di ẹni ìgbàlà, àti pé ẹnìkẹ́ni tí kò bá nĩ gbàgbọ́, ìdájọ́ òdodo yíò wá sí órí nwọn; àti pẹ̀lú bí a bá dá nwọn lẹ́bi nwọn mú ìdálẹ́bi nwọn wá sí órí ara nwọn. Àti nísisìyí ẹ rántí, ẹ rántí, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá ṣègbé, ṣègbé sí ọrùn ara rẹ̀; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì nṣe àìṣedẽdé, nṣe é sí ọrùn ara rẹ̀; nítorí kiyesĩ, ẹ̀yin di òmìnira; a sì gbà pé kí ẹ ṣe bí ẹ ti fẹ́; nítorí ẹ kíyèsĩ, Ọlọ́run ti fún nyín ní ìmọ̀ ó sì ti sọ nyín di òmìnira. Ó sì ti fifún nyín pé kí ẹ̀yin ó lè dá rere mọ̀ nínú búburú; ó sì ti fi fún nyín pé kí ẹ̀yin lè yan ìyè tàbí ikú; àti kí ẹ̀yin le ṣe rere kí a sì mú yín padàbọ̀sípò sí èyítí ó dára, tàbí pé kí a mú èyítí ó dára padàbọ̀sípò sí yín; tàbí kí ẹ̀yin le sé búburú, kí a sì da èyítí ó burú padàbọ̀sípò sí yín. 15 Olúwa bá àwọn ará Nífáì wí nítorítí ó ní ìfẹ́ sí nwọn—Àwọn ará Lámánì tí a yí padà wà ní ìdúróṣinṣin àti ní ìtẹramọ́ nínú ìgbàgbọ́ nwọn—Olúwa yíò ṣãnú fún àwọn ará Lámánì ní ọjọ́ìkẹhìn. Ní ìwọ̀n ọdún 6 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ kíyèsĩ, mo wí fún nyín pé bíkòṣepé ẹ̀yin ronúpìwàdà àwọn ilé nyín yíò di ahoro fún nyín. Bẹ̃ni, bíkòṣepe ẹ̀yin ronúpìwàdà, àwọn obìnrin nyín yíò ní ìdí láti ṣọ̀fọ̀ ní ọjọ́ tí nwọn nfi ọmú fún ọmọ mu; nítorí ẹ̀yin yíò gbìyànjú láti sá kò sì ní sí ibi ìsádi; bẹ̃ni, ègbé sì ni fún àwọn tí ó loyun, nítorítí nwọn yíò wúwo nwọn kò sì ní lè sá; nítorínã nwọn yíò di títẹ̀mọ́lẹ̀ tí a ó sì fi nwọ́n sílẹ̀ láti ṣègbé. Bẹ̃ni, ègbé ni fún àwọn ènìyàn yĩ tí nwọn npè ní àwọn ènìyàn Nífáì bíkòṣepé kí nwọn ó ronúpìwàdà, nígbàtí nwọn yíò rí gbogbo àwọn àmì àti ìyanu wọ̀nyí èyítí a ó fi hàn nwọ́n; nítorí ẹ kíyèsĩ, a ti yàn nwọ́n ní ènìyàn Olúwa; bẹ̃ni, àwọn ènìyàn Nífáì ni ó ti nífẹ sí, ó sì ti bá nwọn wí; bẹ̃ni, ní ọjọ́ ìwà àìṣedẽdé nwọn ni ó bá nwọn wí nítorítí ó nífẹ sí nwọn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ ẹ̀yin arákùnrin mi, àwọn ará Lámánì ni ó kórìra nítorítí ìṣe nwọn jẹ́ èyítí ó burú títí, èyítí ó rí bẹ̃ nítorí àìṣedẽdé inú àṣà àwọn bàbá nwọn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ìgbàlà ti wá sí órí nwọn nípasẹ̀ ìwãsù àwọn ará Nífáì; àti nítorínã ni Olúwa ṣe mú ọjọ́ nwọn gùn. Èmi sì fẹ́ kí ẹ̀yin ó rí i pé èyítí ó pọ̀ jù nínú nwọn ni ó ní ọ̀nà tí ó dára, tí nwọ́n sì nrìn ní ọ̀nà òtítọ́ níwájú Ọlọ́run, tí nwọ́n sì gbìyànjú láti pa àwọn òfin rẹ̀ àti àwọn ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú òfin Mósè. Bẹ̃ni, mo wí fún nyín, pé èyítí ó pọ̀ jù nínú nwọn ni ó nṣe èyí, tí nwọ́n sì ngbìyànjú láìkáarẹ̀ láti mú àwọn arákùnrin nwọn yókù sínú ìmọ̀ òtítọ́; nítorínã àwọn tí ó pọ̀ sì darapọ̀ mọ́ nwọn lójojúmọ́. Ẹ sì kíyèsĩ, ẹ̀yin mọ̀ fúnra nyín, nítorítí ẹ̀yin ti fi ojú ríi, pé gbogbo àwọn tí a mú sínú ìmọ̀ òtítọ́ nínú nwọn, àti lati mọ̀ nípa àṣà búburú tí ó sì jẹ́ ìríra tí àwọn bàbá nwọn, tí a sì darí nwọn láti gba àwọn ìwé-mímọ́ gbọ́, bẹ̃ni, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wòlĩ mímọ́, èyítí a kọ, èyítí ó ndarí nwọn sí ìgbàgbọ́ nínú Olúwa, àti sí ìrònúpìwàdà, ìgbàgbọ́ àti ìrònúpìwàdà nã sì mú ìyílọ́kànpadà sínú nwọn— Nítorínã, gbogbo àwọn tí ó rí bayĩ, ẹ̀yin mọ̀ fúnra nyín pé àwọn wà ní ìdúróṣinṣin àti ní ìtẹramọ́ nínú ìgbàgbọ́ nã, àti nínú ohun nã nípasẹ̀ èyítí a ti sọ nwọ́n di òmìnira. Ẹ̀yin sì mọ̀ pẹ̀lú pé nwọ́n ti ri àwọn ohun ìjà ogun nwọn mọ́lẹ̀, nwọ́n sì bẹ̀rù láti tún gbé nwọn pé kí nwọn ó máṣe dẹ́ṣẹ̀; bẹ̃ni, ẹ̀yin ríi pé nwọ́n bẹ̀rù láti dẹ́ṣẹ̀—nítorí ẹ kíyèsĩ nwọn yíò gbà kí àwọn ọ̀tá nwọn ó tẹ̀ nwọ́n mọ́lẹ̀ kí nwọn ó sì pa nwọ́n, nwọn kò sì ni gbe idà wọn sókè sí wọn, èyí sì rí bẹ̃ nítorí ìgbàgbọ́ nwọn nínú Krístì. Àti nísisìyí, nítorí ìdúróṣinṣin nwọn nígbàtí nwọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ohun nã tí nwọ́n gbà gbọ́, nítorípé nítorí ìdúróṣinṣin nwọn nígbàtí nwọ́n ti rí ìmọ́lẹ̀, ẹ kíyèsĩ, Olúwa yíò bùkúnfún nwọn yíòsì mú ọjọ́ nwọn gùn, l’áìṣírò ìwà àìṣedẽdé nwọn— Bẹ̃ni, bí nwọ́n tilẹ̀ jó rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ Olúwa yíò mú ọjọ́ nwọn gùn, títí àkokò nã yíò dé èyítí àwọn bàbá nlá wa ti sọ nípa rẹ àti wòlĩ Sénọ́sì, àti àwọn wòlĩ míràn tí ó pọ̀, nípa ìdápadà sí ipò àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì lẹ̃kan síi sí ìmọ̀ òtítọ́— Bẹ̃ni, mo wí fún nyín, pé ní ìgbà ìkẹhìn ìlérí Olúwa yíò de ọdọ àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì; l’áìṣírò àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú tí nwọn yíò sí ní, àti l’áìṣírò a ó lé nwọn sihinsọhun lórí ilẹ̀ ayé, tí a ó sì dọdẹ nwọn, tí a ó sì lù nwọ́n àti fọ́n nwọn kãkiri, tí nwọn kò sì ní ní ibi ìsádi, Olúwa yíò ṣãnú fún nwọn. Èyí sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìsọtẹ́lẹ̀ nã, pé a ó tún mú nwọn padà sínú ìmọ̀ òtítọ́, èyítí í ṣe ìmọ̀ nípa Olùràpadà nwọn, àti Olùṣọ́-àgùtàn òtítọ́ nwọn tí ó tóbi, tí a ó sì kà nwọ́n mọ́ àwọn àgùtàn rẹ̀. Nítorínã mo wí fún nyín, yíò sàn fún nwọn ju ẹ̀yin lọ bíkòṣepé ẹ̀yin ronúpìwàdà. Nítorí ẹ kíyèsĩ, bí ó bá ṣe wípé a ti fi iṣẹ́ ìyanu nã hàn nwọ́n èyítí a ti fi hàn nyín, bẹ̃ni, han àwọn nã tí nwọ́n ti rẹ́hìn nínú ìgbàgbọ́ nítorí àwọn àṣà àwọn bàbá nwọn, ẹ̀yin ríi fúnra nyín pé nwọn kò ní rẹ́hìn mọ́ nínú ìgbàgbọ́. Nítorínã, ni Olúwa wí: Èmi kì yíò pa nwọ́n run pátápátá ṣùgbọ́n èmi yíò mú kí nwọn ó tún padà sí ọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ tí ó bá yẹ, ni Olúwa wí. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ni Olúwa wí, nípa àwọn ará Nífáì: Bí nwọn kò bá ronúpìwàdà, kí nwọ́n sì ṣe ìfẹ́ mi, èmi yíò pa nwọ́n run pátápátá, ni Olúwa wí, nítorí àìgbàgbọ́ nwọn l’áìṣírò àwọn iṣẹ́ nlá tí mo ti ṣe lãrín nwọn; bí Olúwa sì ti wà lãyè ni àwọn ohun wọ̀nyí yíò rí, ni Olúwa wí. 16 Àwọn ará Nífáì tí ó gba Sámúẹ́lì gbọ́ ni Nífáì rìbọmi—Àwọn ọfà àti àwọn òkúta wẹ́wẹ́ àwọn aláìronúpìwàdà ará Nífáì kò lè pa Sámúẹ́lì—Nínú nwọn sé ọkàn nwọn le, àwọn míràn sì rí àwọn ángẹ́lì—Àwọn aláìgbàgbọ́ sọ wípé kò bá ipa ọgbọ́n mu láti gbàgbọ́ nínú Krístì àti bíbọ̀ rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Ní ìwọ̀n ọdún 6 sí 1 kí a tó bí Olúwa wa. Àti nísisìyí, ó sì ṣe tí àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì, ará Lámánì pọ̀, èyítí ó sọ lórí ògiri ìlú-nlá nã. Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde lọ nwọ́n sì nwá Nífáì; nígbàtí nwọ́n sì ti jáde lọ tí nwọ́n sì wáa rí nwọ́n jẹ́wọ́ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ nwọn fún un nwọn kò sì sẹ́, nwọ́n sì fẹ́ kí a rì wọn bọmi sí Olúwa. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì gbọ́ bínú síi; nwọ́n sì sọ ọ́ ní okuta lórí ògiri nã, àti pẹ̀lú púpọ̀ ta ọfà bã bí ó ti dúró lórí ògiri nã; ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, tóbẹ̃ tí òkúta nwọn kò bã bẹ̃ nã ni ọfà nwọn. Nísisìyí nígbàtí nwọ́n ríi pé àwọn ohun tí nwọ́n nsọ lù ú kò bã, àwọn tí ó sì gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́pọ̀ síi, tóbẹ̃ tí nwọ́n sì kọjá lọ bá Nífáì kí ó lè rì nwọn bọmi. Nítorí ẹ kíyèsĩ, Nífáì nṣe ìrìbọmi, ó sì nsọtẹ́lẹ̀, ó sì nwãsù, tí ó nkígbe ìrònúpìwàdà sí àwọn ènìyàn nã, tí ó sì nfi àwọn àmì àti ohun ìyanu hàn, tí ó sì nṣe iṣẹ́ ìyanu lãrín àwọn ènìyàn nã, pé kí nwọ́n lè mọ̀ pé Krístì nã yíò dé láìpẹ́— Tí ó sì nsọ nípa àwọn ohun tí nbọ̀wá láìpẹ́, kí nwọn ó lè mọ̀ àti kí nwọn o rántí ní ìgbà tí nwọ́n bá dé pé a ti sọ nwọ́n di mímọ̀ fún nwọn ṣãjú, láti lè mú kí nwọn ó gbàgbọ́; nítorínã gbogbo àwọn tí ó gba ọ̀rọ̀ Sámúẹlì gbọ́ jáde lọ bã láti ṣe ìrìbọmi, nítorítí nwọ́n wá ní ironúpìwàdà àti ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nwọn. Ṣùgbọ́n èyítí ó pọ̀ jù nínú nwọn kò gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì; nítorínã nígbàtí nwọ́n ríi pé àwọn òkúta nwọn àti ọfà nwọn kò lè bã nwọn kígbe pe àwọn olórí nwọn, wípé: Ẹ mú ọkùnrin yĩ, kí ẹ sì dẽ, nítorí ẹ kíyèsĩ ó ní èṣù nínú; àti nítorí agbára èṣù tí ó wà nínú rẹ̀ àwa kò lè sọ àwọn òkúta wa àti ọfà wa bà á; nítorínã ẹ mú u kí ẹ sì dè é, kí ẹ sì múu lọ. Bí nwọ́n sì ti nlọ láti mú u, ẹ kíyèsĩ, ó bẹ́ sílẹ̀ láti orí ògiri nã, ó sì sálọ kúrò nínú ilẹ̀ nwọn, bẹ̃ni, àní lọ sínú ilẹ̀ tirẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀sí wãsù àti láti sọtẹ́lẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀. Sì kíyèsĩ, a kò sì gburo rẹ̀ mọ́ lãrín àwọn ará Nífáì; báyĩ sì ni ìṣe àwọn ènìyàn nã rí. Báyĩ sì ini ọdún kẹrìndínlãdọ́run nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí. Báyĩ sì ni ọdún kẹtàdínlãdọ́run nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ parí pẹ̀lú, tí èyítí ó pọ̀ jù nínú àwọn ènìyàn nã wà nínú ìgbéraga àti ìwà búburú nwọn, tí díẹ̀ nínú nwọn sì nrìn ní ìkíyèsára níwájú Ọlọ́run. Bí àwọn nkan ti rí sì nìyí pẹ̀lú, ní ọdún kejìdínlãdọ́run nínú ìjọba àwọn onídàjọ́. Díẹ̀ sì ni ìyípadà tí ó wà nínú ìṣe àwọn ènìyàn nã, bíkòṣepé àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí sé àyà nwọn le nínú àìṣedẽdé, tí nwọ́n sì túbọ̀ nṣe-èyítí ó lòdì sí òfin Ọlọ́run, ní ọdún kọkàndínlãdọ́run nínú ìjọba àwọn onídàjọ́. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe ní ãdọ́run ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí a fún àwọn ènìyàn nã ní àwọn àmì nlá, àti àwọn ohun ìyanu; tí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ sì bẹ̀rẹ̀ sí di mímúṣẹ. Àwọn ángẹ́lì sì farahàn sì áwọn ènìyàn, àwọn ọlọgbọ́n ènìyàn, tí nwọ́n sì mú ìròhìn ayọ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ inúdídùn wa fún nwọn; báyĩ sì ni àwọn ìwémímọ́ bẹ̀rẹ̀sí di mímúṣẹ nínú ọdún yĩ. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí sé ọkàn nwọn lè, gbogbo nwọn bíkòṣe àwọn tí ó gbàgbọ́ jùlọ nínú nwọn, àti lára àwọn ará Nífáì àti lára àwọn ará Lámánì pẹ̀lú, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gbójúlé agbára ara nwọn àti ọgbọ́n ara nwọn, wípé: Àwọn ohun kan ni nwọ́n rò tí ó sì ṣe dẽdé, lãrín àwọn ohun tí ó pọ̀; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àwá mọ̀ pé gbogbo àwọn iṣẹ́ nlá àti ìyanu yĩ kò lè ṣẹ, nípa èyítí nwọ́n ti sọ. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe àròyé nwọn sì njiyàn lãrín ara nwọn, wípé: Pé kò jẹ́ ohun tí ó tọ́ pé kí ènìyàn kan bĩ Krístì kan yíò wá; bí ó bá sì rí bẹ̃, tí í sì í ṣe Ọmọ Ọlọ́run, Bàbá ọ̀run àti ayé, bí nwọ́n ti wíi, ẽṣe ti kò ha fi ara rẹ̀ hàn sí àwa nã gẹ́gẹ́bí yíò ti fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn tí yíò wà ní Jerúsálẹ́mù? Bẹ̃ni, ẽṣe tí kò hà ní fi ara rẹ̀ hàn ní ilẹ̀ yĩ gẹ́gẹ́bí yíò ti ṣe ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù? Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àwá mọ̀ pé àṣà búburú ni èyí, èyítí àwọn bàbá nlá wa ti fi lé wa lọ́wọ́, láti mú wa gbàgbọ́ nínú àwọn ohun nlá àti ìyanu nã èyítí nbọ̀wá, tí kĩ ṣe lãrín wa, ṣùgbọ́n nínú ilẹ̀ kan tí ó wà lókẽrè, ilẹ̀ èyítí àwa kò mọ̀; nítorínã kí nwọn lé fi wá sílẹ̀ nínú àìmọ̀, nítorítí àwa kò fi ojú ríi pé òtítọ́ ni nwọ́n í ṣe. Nwọn yíò sì ṣe ohun ìyanu nlá kan tí kò lè yé wa nípasẹ̀ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ àti ọ̀nà ẹni búburú nnì èyítí yíò mú wa mọ́lẹ̀ láti jẹ́ ẹrú sí ọ̀rọ̀ nwọn, àti ẹ̀rù sí nwọn, nítorítí àwa gbẹ́kẹ̀lé nwọn láti kọ́ wa ní ọ̀rọ̀ nã; báyĩ ni nwọn yíò sì fi wá sí ipò àìmọ̀ bí àwa bá jọ̀wọ́ ara wa fún wọn, ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó pọ̀ síi sì ní àwọn ènìyàn nã tún rò nínú ọkàn nwọn, èyítí ó jẹ́ ti aláìgbọ́n àti ásán; nwọ́n sì dãmú púpọ̀, nítorítí Sátánì sì rú nwọn sókè láti ṣe àìṣedẽdé nígbà-gbogbo; bẹ̃ni, ó nlọ kiri láti tan irọ́ àti asọ̀ kálẹ̀ lórí ilẹ̀ nã, kí ó lè sé ọkàn àwọn ènìyàn nã le sí èyítí ó dára àti sí èyítí nbọ̀wá. Àti l’áìṣírò àwọn àmì àti ohun ìyanu tí nwọ́n ṣe lãrín àwọn ènìyàn Olúwa, àti àwọn iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ tí nwọ́n ṣe, Sátánì ní agbára lórí ọkàn àwọn ènìyàn nã tí ó wà lórí gbogbo ilẹ̀ nã. Báyĩ sì ni ãdọ́rún ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí. Báyĩ sì ni ìwé Hẹ́lámánì, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ Hẹ́lámánì àti àwọn ọmọ rẹ̀ parí. Nífáì Kẹ́ta 1 Nífáì, ọmọ Hẹ́lámánì, jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã, ọmọ rẹ̀ Nífáì sì nkọ àwọn àkọsílẹ̀ nã pamọ́—Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn àmì àti ohun ìyanu pọ̀ púpọ̀, àwọn ènìyàn búburú pa ète láti pa àwọn olódodo—Alẹ́ ọjọ́ bíbíKrístì dé—A fún nwọn ní àmì nã, ìràwọ̀ titun sì yọ—Irọ́pípa àti ẹ̀tàn pọ̀ síi, àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Ní ìwọ̀n ọdún 1–4 nínú ọjọ́ Olúwa wa. NÍSISÌYÍ ó sì ṣe tí ọdún kọkànlélãdọ́rún ti kọjá tí ó sì di ẹgbẹ̀ta ọdún láti ìgbà tí Léhì fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀; o sì tún jẹ́ ọdún tí Lákónéúsì jẹ́ adájọ́ àgbà àti bãlẹ̀ lórí ilẹ̀ nã. Àti Nífáì, ọmọ Hẹ́lámánì, sì ti jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí ó sì ti fún ọmọ rẹ Nífáì ní ojuṣe, ẹnití íṣe ọmọ rẹ̀ àkọ́bí ọkùnrin, nípa àwọn àwo idẹ̀, àti gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ tí nwọ́n ti kọ ṣíwájú, àti gbogbo àwọn ohun t í nwọ́n t i pamọ́ ní mímọ́ láti ìgbà tí Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Nígbànã ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ nã, ibití ó sì lọ, ẹnìkan kò mọ̀; ọmọ rẹ̀ Nífáì sì kọ àwọn àkọsílẹ̀ nã pamọ́ dípò rẹ̀, bẹ̃ni, àkọsílẹ̀ nípa àwọn ènìyàn yĩ. Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kejìlélãdọ́rún, ẹ kíyèsĩ, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ti àwọn wòlĩ bẹ̀rẹ̀sí di mìmúṣẹ síi ní kíkún; nítorítí àwọn ohun àmì tí ó tóbí síi àti ohun ìyanu tí ó tóbi síi ni ó ndi ṣíṣe lãrín àwọn ènìyàn nã. Ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ wà tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí sọ wípé àkokò nã ti kọjá fún àwọn ọ̀rọ̀ nã láti di mìmúṣẹ, èyítí Sámúẹ́lì, ará Lámánì ti sọ. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí yọ̀ lórí àwọn arákùnrin nwọn, tí nwọ́n ńsọ wípé: Ẹ kíyèsĩ àkokò nã ti kọjá, àwọn ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì kò sì ṣẹ; nítorínã, ayọ̀ nyín àti ìgbàgbọ́ nyín nípa ohun yĩ ti jẹ́ lásán. Ó sì ṣe tí nwọn npariwo nlá jákè-jádò ilẹ̀ nã; àwọn ènìyàn tí ó sì gbàgbọ́ sì bẹ̀rẹ̀sí kún fún ìbànújẹ́ pupọ̀, ní ìbẹ̀rù pé ni ọ̀nàkọnà àwọn ohun tí a ti sọ nnì lè ṣàì di mímúṣẹ. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, nwọ́n nṣọ́nà ní ìdúró sinsin fún ọjọ́ nã àti òru nã àti ọjọ́ nã tí yíò rí bí ọjọ́ kan bí èyítí kò ní òru, kí nwọn ó lè mọ̀ pé ìgbàgbọ́ nwọn kò wà lásán. Nísisìyí ó sì ṣe tí ọjọ́ kan wà tí àwọn aláìgbàgbọ́ ènìyàn yà sọ́tọ, pé kí gbogbo àwọn ẹnití ó gbàgbọ́ nínú àwọn àṣà nnì ni kí nwọn ó pa, àfi bí àmì nã bá wa si ìmúṣẹ, èyítí wòlĩ Sámúẹ́lì ti fún nwọn. Nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Nífáì, ọmọ Nífáì, rí ìwà búburú àwọn ènìyàn rẹ̀ yĩ, ọkàn rẹ̀ kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó sì ṣe tí ó jáde lọ tí ó sì wólẹ̀ lórí ilẹ̀, tí ó sì kígbe kíkan-kíkan pè Ọlọ́run rẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̃ni, àwọn tí nwọ́n ti fẹ́rẹ̀ di píparun nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú àṣà àwọn bàbá wọn. Ó sì ṣe tí ó kígbe kíkan-kíkan pe Olúwa ni gbogbo ọjọ́ nã; ẹ sì kíyèsĩ, ohùn Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá ti o nsọ wípé: Gbé orí rẹ sókè kí ó sì tújúká; nítorí kíyèsĩ, àkokò nã ti dé tán, ní òru òní ni a o fún nyín ní àmì nã, àti ní ọ̀la ni èmi yíò wá sínú ayé, láti fi hàn fún ayé pé èmi yíò ṣe ìmúṣẹ gbogbo àwọn ohun tí èmi ti mú kí a sọ láti ẹnu àwọn wòlĩ mímọ́ mi. Kíyèsĩ, èmi tọ àwọn tí íṣe tèmi wá, láti ṣe ìmúṣẹ gbogbo àwọn ohun tí èmi ti sọ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, àti láti ṣe ìfẹ́ ti Bàbá àti ti Ọmọ—ti Bàbá nítorí mi, àti tiỌmọ nítorí ẹran ara mi. Sì kíyèsĩ, àkokò nã ti dé tán, lóru òní ni a ó sì fún nyín ní àmì nã. Ó sì ṣe tí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ Nífáì wá di mìmúṣẹ, gẹ́gẹ́bí a ti sọ wọ́n; nítorí ẹ kíyèsĩ, nígbàtí ó di àṣálẹ́ kò sí òkùnkùn; ẹnu sì bẹ̀rẹ̀ sí yà àwọn ènìyàn nã nítorípé kò sí òkùnkùn nígbàtí alẹ́ lẹ́. Àwọn tí kò sì gba ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ gbọ́ sì pọ̀, tí nwọ́n wó lulẹ̀ tí nwọ́n sì dàbí ẹ̀nítí ó ti kú, nítorítí nwọ́n mọ̀ pé ète ìparun nlá èyítí nwọ́n ti tẹ́ sílẹ̀ fún àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ ti di asán; nítorítí àmì nã èyítí a ti fún nwọn ti dé. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí mọ̀ wípé Ọmọ Ọlọ́run yíò farahàn láìpẹ́ dandan; bẹ̃ni, ní kúkúrú, gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé gbogbo láti ìwọ oòrùn dé ìlà oòrùn, àti ní ilẹ̀ apá àríwá àti ní ilẹ̀ apá gúsù, ni ẹnu yà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀ tí nwọ́n sì wó lulẹ̀. Nítorí nwọ́n mọ̀ pé àwọn wòlĩ ti jẹ́risí àwọn ohun wọ̀nyí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àti pé àmì nã èyítí a ti fi fun nwọn ti dé; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀rù nítorí àìṣedẽdé nwọn àti àìgbàgbọ́ nwọn. Ó sì ṣe tí òkùnkùn kò sí ní gbogbo òru nã, ṣùgbọ́n tí ó mọ́lẹ̀ bí èyítí íṣe ọ̀sán gangan. Ó sì ṣe tí oòrùn sì tún yọ ní òwúrọ̀, gẹ́gẹ́bí ó ti yẹ kí ó rí; nwọ́n sì mọ̀ wípé ọjọ́ nã ni a bí Olúwa, nítorí àmì nã èyítí a ti fún ni. Ó sì ṣe, bẹ̃ni, ohun gbogbo, títí dé èyítí ó kéré jùlọ, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ. Ó sì ṣe pẹ̀lú tí ìràwọ̀ titun kan yọ, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ nã. Ó sì ṣe pé láti ìgbà yĩ lọ ni irọ́ bẹ̀rẹ̀sí jáde wá láti ẹnu àwọn ènìyàn nã, láti ọwọ́ Sátánì, láti sé àyà nwọn le, pé kí nwọn ó má bã gbàgbọ́ nínú àwọn àmì àti ohun ìyanu èyítí nwọ́n ti rí; ṣùgbọ́n l’áìṣírò àwọn irọ́ àti ẹ̀tàn wọ̀nyí èyítí ó pọ̀ jù nínú àwọn ènìyàn nã ni ó gbàgbọ́, tí a sì yí nwọn lọ́kàn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa. Ó sì ṣe tí Nífáì kọjá lọ lãrín àwọn ènìyàn nã, àti àwọn míràn pẹ̀lú, tí nwọ́n nṣe ìrìbọmi sí ìrònúpìwàdà, nínú èyítí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tóbi wà. Báyĩ sì ni àwọn ènìyàn nã tún bẹ̀rẹ̀ si ní àlãfíà lórí ilẹ̀ nã. Kò sì sí asọ̀, bíkòṣe ní ti àwọn ènìyàn díẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀sí wãsù, tí nwọn nsa ipá láti lè làdí rẹ̀ nípa àwọn ìwé-mímọ́ pé kò tọ̀nà mọ́ láti pa òfin Mósè mọ́. Nísisìyí nínú ohun yĩ, nwọ́n ṣìnà, nítorítí àwọn ìwé-mímọ́ kò yé nwọn. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí ọ́kàn nwọ́n yí padà láìpẹ́, tí nwọ́n sì ní ìdánilójú nípa ti ìṣìnà nínú èyítí nwọ́n wà, nítorítí a jẹ́ kí o di mímọ̀ fún nwọ́n pé òfin nã kò tĩ di mímúṣẹ, àti pé ó níláti di mímúṣẹ títí dé èyítí ó kéré jùlọ; bẹ̃ni, ọ̀rọ̀ nã tọ̀ nwọ́n wá pé ó níláti di mímúṣẹ; bẹ̃ni, wípé ohun kíkiní tabi kékeré kan kì yíò kọjá lọ títí yíò fi di mímúṣẹ pátápátá; nítorínã nínú ọdún yĩ kannã ni a mú nwọ́n sínú ìmọ̀ ìṣìnà nwọn àti tí nwọ́n sì jẹ́wọ́ àṣìṣe nwọn. Báyĩ sì ni ọdún kejìlélãdọ́rún kọjá, èyítí ó mú ìròhìn ayọ̀ bá àwọn ènìyàn nã nítorí àwọn àmì èyítí nwọ́n ti di mímúṣẹ, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́. Ó sì ṣe tí ọdún kẹtàlélãdọ́run nã sì kọjá ní àlãfíà, bíkòṣe fún àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì, tí nwọn ngbé lórí àwọn òkè gíga, tí nwọ́n sì nyọ ilẹ̀ nã lẹ́nu; nítorítí àwọn ibi gíga nwọn àti àwọn ibi ìkọ̀kọ̀ nwọn lágbára tóbẹ̃ tí àwọn ènìyàn nã kò lè borí nwọn; nítorínã nwọ́n sì ṣe ìpànìyàn púpọ̀púpọ̀, tí nwọ́n sì pa àwọn ènìyàn nã ní ìpakúpa. Ó sì ṣe nínú ọdún kẹ́rinlélãdọ́rún tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí pọ̀ síi, ní ìlọ́po ìwọ̀n, nítorípé àwọn olùyapakúrò lãrín àwọn ará Nífáì púpọ̀ ni ó sá lọ bá nwọn, èyítí ó mú kí ìrora-ọkàn púpọ̀ ó bá àwọn ará Nífáì tí ó kù lórí ilẹ̀ nã. Ohun kan sì wà tí ó mú kí ìrora-ọkàn ó wà lãrín àwọn ará Lámánì; nítorí kíyèsĩ, nwọ́n ní àwọn ọmọ púpọ̀ tí nwọ́n dàgbà tí nwọ́n sì nlọ́jọ́ lórí, tí nwọ́n sì di ẹni ara nwọn, tí àwọn ènìyàn kan tí íṣe ará Sórámù sì ṣì nwọ́n lọ́nà, nípa irọ́ pípa nwọn àti àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn nwọn, láti darapọ̀ mọ́ àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì nnì. Báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì ṣe rí ìpọ́njú pẹ̀lú, tí nwọn sì bẹ̀rẹ̀sí fà sẹ́hìn nínú ìgbàgbọ́ àti ìwà òdodo nwọn, nítorí ìwà búburú ìran tí ó ndìde. 2 Ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra npọ̀ síi lãrín àwọn ènìyàn nã—Àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì darapọ̀ láti dãbò bò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì—Àwọn ará Lámánì tí a ti yí lọ́kàn padà di afúnláwọ̀ a sì npè wọ́n ní ará Nífáì. Ní ìwọ̀n ọdún 5 sí 16 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Ó sì ṣe ní báyĩ tí ọdún karundinlọgọrun kọjá pẹ̀lú, tí àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí gbàgbé àwọn àmì àti ohun ìyanu èyítí nwọn ti gbọ́ nípa nwọn, tí àdínkù sì nwà síi nínú ìyàlẹ́nu nípa ohun àmì tàbí ohun ìyanu láti ọ̀run wá, tóbẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí le nínú ọkàn nwọn, àti tí nwọ́n sì fọ́jú nínú ẹ̀mí nwọn, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe áláìgbàgbọ́ àwọn ohun wọ̀nyí èyítí nwọn ti gbọ́ àti tí nwọn ti rí— Tí nwọ́n sì ngbèrò ohun asán nínú ọkàn wọn, wípé àwọn ènìyàn ni ó ṣe nwọ́n nípa agbára èṣù, láti ṣì nwọ́n lọ́nà àti láti tàn ọkàn àwọn ènìyàn nã; báyĩ sì ni Sátánì tún gba ọkàn àwọn ènìyàn nã ní ìní, tóbẹ̃ tí ó fọ́ nwọ́n lójú tí ó sì ṣì wọ́n lọ́nà láti gbàgbọ́ pé ẹ̀kọ́ Krístì jẹ́ ohun aṣiwèrè àti ohun asán. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí lágbára síi nínú ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra; tí nwọn ko sì gbàgbọ́ pé a fún nwọn ní àwọn àmì àti ohun ìyanu síi; tí Sátánì sì nlọ kiri, tí ó nmú ọkàn àwọn ènìyàn nã ṣìnà, tí ó ndán wọn wò, àti tí ó nmú kí nwọn ó hùwà búburú nlá lórí ilẹ̀ nã. Báyĩ sì ni ọdún kẹrindinlọgọrun kọjá; àti ọdún kẹtàdínlọ́gọ̀rún; àti ọdún kejìdínlọ́gọ̀rún pẹ̀lú; àti ọdún kọkàndínlọ́gọ̀rún; Àti ọgọ́rún ọdún pẹ̀lú ni ó ti kọjá láti ìgbà Mòsíà, ẹnití íṣe ọba lórí àwọn ènìyàn ará Nífáì ní àkokò kan rí. Ẹgbẹ̀ta ọdún àti mẹ́sán sì ti kọjá lẹ́hìn tí Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Ọdún mẹ́sán sì ti kọjá láti ìgbà tí a ti fún nwọn ní àmì nã, èyítí àwọn wòlĩ ti sọ nípa rẹ̀, pé Krístì yíò wá sínú ayé. Nísisìyí àwọn ará Nífáì bẹ̀rẹ̀sí ṣírò ọjọ́ nwọn láti ìgbà yĩ tí a ti fún nwọn ní àmì nã, tàbí láti ìgbà tí Krístì ti dé; nítorínã, ọdún mẹ́sán ti kọjá. Nífáì, ẹnití íṣe bàbá Nífáì, ẹnití ó ni àwọn àkọsílẹ̀ nã ní ìtọ́jú, kò sì padà sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, a kò sì ríi mọ́ níbikíbi ní gbogbo ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã sì dúró nínú ipò ìwà búburú síbẹ̀, l’áìṣírò ìkàsí fún ìwãsù àti ìsọtẹ́lẹ̀ tí ó pọ̀ èyítí a fi ránṣẹ́ lãrín nwọn; báyĩ sì ni ọdún kẹẹ̀wá kọjá pẹ̀lú; ọdún kọkànlá nã sì kọjá pẹ̀lú nínú ipò àìṣedẽdé. Ó sì ṣe ní ọdún kẹtàlá tí àwọn ogun àti ìjà bẹ̀rẹ̀sí wà jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã; nítorítí àwọn ọlọ́ṣà Gàdíátónì ti pọ̀ púpọ̀, tí nwọ́n sì pa púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n sì run ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá, tí nwọ́n sì tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikú àti ìpakúpa ènìyàn jákè-jádò ilẹ̀ nã, tí ó fi di èyítí ó tọ́ kí gbogbo àwọn ènìyàn nã, àti àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì, kí nwọn ó gbé ohun ìjà-ogun láti dojú kọ nwọn. Nítorí nã, gbogbo àwọn ará Lámánì tí nwọ́n ti di ẹnití a yí lọ́kàn padà sí ọ́dọ̀ Olúwa sì darapọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Nífáì, nwọ́n sì níláti gbé ohun ìjà-ogun kọlũ àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì nnì, fún ìdãbò bò ẹ̀mí nwọn àti àwọn obirin nwọn àti àwọn ọmọ nwọ́n, bẹ̃ni, àti láti di ẹ̀tọ́ nwọn mú, àti àwọn ànfàní ìjọ nwọn àti ti ìjọsìn nwọn, àti ominira nwọn àti ìdásílẹ̀ nwọn. Ó sì ṣe, kí ọdún kẹtàlá yĩ ó tó kọjá, a dẹ́rùba àwọn ará Nífáì pẹ̀lú ìparun pátápátá nitorí ogun yĩ, èyítí ó ti di kíkan jùlọ. Ó sì ṣe tí a ka àwọn ará Lámánì nnì tí nwọ́n ti darapọ̀ mọ́ àwọn ará Nífáì; A sì mú ègún kúrò lórí nwọn, tí àwọ̀ ara nwọn sì di funfun gẹ́gẹ́bí ti àwọn ará Nífáì; Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin nwọn sì lẹ́wà púpọ̀púpọ̀, a sì kà nwọ́n mọ́ àwọn ará Nífáì, a sì pè nwọ́n ní ará Nífáì. Báyĩ sì ni ọdún kẹtàlá parí. Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹrìnlá, ogun èyítí ó wà lãrín àwọn ọlọ́ṣà nã àti àwọn ènìyàn Nífáì sì tẹ̀síwájú tí ó sì di kíkan lọ́pọ̀lọpọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ènìyàn Nífáì borí àwọn ọlọ́ṣà nã, tóbẹ̃ tí nwọ́n lé nwọn padà jáde kúrò lórí ilẹ̀ nwọn lọ sínú àwọn òkè gíga àti lọ sínú àwọn ibi ìkọ̀kọ̀ nwọn. Báyĩ sì ni ọdún kẹrìnlá nã parí. Ní ọdún kẹẹ̀dọ́gún ni nwọ́n sì jáde kọlũ àwọn ènìyàn Nífáì; àti nitori ìwà búburú àwọn ènìyàn Nífáì, àti àwọn ìjà àti ìyapa nwọn tí ó pọ̀, àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì nã sì borí nwọn lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Báyĩ sì ni ọdún kẹẹ̀dógún parí, báyĩ sì ni àwọn ènìyàn nã wà ní ipò ìpọ́njú tí ó pọ̀; tí idà ìparun sì gbé sókè sí nwọn, tóbẹ̃ tí ó ti fẹ́rẹ̀ ké nwọn lulẹ̀, ó sì rí bẹ̃ nítorí ìwà àìṣedẽdé nwọn. 3 Gídíánhì, olórí àwọn Gádíátónì, fi agbára bẽrè pé kí Lákónéúsì àti àwọn ará Nífáì jọ̀wọ́ ara nwọn àti àwọn ilẹ̀ nwọn sílẹ̀—Lákónéúsì yàn Gídgídónì gẹ́gẹ́bí olórí-ológun àgbà fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun—Àwọn a r á N í f á ì p é j ọ pọ̀ s í Sarahẹ́múlà àti Ibi-Ọ̀pọ̀ láti dãbò bò ara wọn. Ní ìwọ̀n ọdún 16 sí 18 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ọdún kẹrìndínlógún sí ìgbà tí Krístì ti dé, Lákónéúsì, bãlẹ̀ ilẹ̀ nã, sì rí ìwé kan gbà láti ọwọ́ olórí àti bãlẹ àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà yĩ; àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kọ, wípé: Lákónéúsì, bãlẹ àgbà ilẹ̀ wa àti ẹni olọ́lá jùlọ, kíyèsĩ, mo kọ èpístélì yĩ sí ọ́, mo sì yìn ọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ìdúróṣinṣin rẹ, àti ìdúróṣinṣin àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú, ní dídi èyítí ẹ̀yin rò wípé ó jẹ́ ẹ̀tọ́ àti òmìnira nyín mú; bẹ̃ni, ẹ̀yin duro gbọin-gbọin, bí ẹnipé òrìṣà kan ràn nyín lọ́wọ́, nínú ìdãbò òmìnira nyín, àti ohun ìní nyín, àti ìlú nyín, tàbí èyítí ẹ̀yin npè bẹ̃. Ó sì jẹ́ ohun ìkãnú fún mi, Lákónéúsì ẹni ọlọ́lá jùlọ, pé ìwọ yíò jẹ́ aṣiwèrè àti agbéraga tóbẹ̃ tí o lè rò pé ìwọ lè dojúkọ àwọn ẹnití ó ní ìgboyà tí ó pọ̀ báyĩ tí ó wà ní abẹ́ àṣẹ mi, tí nwọ́n duro ni àkókò yi nínú ohun ìjà nwọn, tí nwọ́n sì ndúró pẹ̀lú ìtara fún àṣẹ nã pé—Ẹ lọ láti kọlu àwọn ará Nífáì kí ẹ sì pa nwọ́n run. Nítorípé èmi sì mọ̀ nípa ìgboyà nwọn pé kò sí ẹnití ó lè borí nwọn; nítorítí mo ti dán wọn wò lójú ogun, àti nítorípé èmi mọ̀ nípa ìkórira títí ayé tí nwọ́n ní sí yín nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà ìpanilára tí ẹ̀yin ti hù sí wọn, nítorínã bí nwọ́n bá wá láti kọlù yín nwọn yíò bẹ̀ yín wò pẹ̀lú ìparun pátápátá. Nítorínã ni èmi ṣe kọ èpístélì yĩ, tí mo fi èdìdí dĩ pẹ̀lú ọwọ́ ara mi, nítorípé mo ní ìtara fún àlãfíà yín, nítorí ìdúróṣinṣin yìn nínú èyítí ẹyìn gbàgbọ́ pé ó tọ̀nà, àti ẹ̀mí yín tí ó lọ́lá ní ojú ogun. Nítorínã ni èmi ṣe kọ ìwé sí yín, nítorípé mo fẹ́ kí ẹ̀yin ó jọ̀wọ́ àwọn ìlú-nlá yín, àwọn ilẹ̀ yín, àti àwọn ohun ìní yín fún àwọn ènìyàn mi yĩ, ju kí nwọn ó fi idà bẹ̀ yín wò tí ìparun yíò sì bá yín. Tàbí ní ọ̀rọ̀ míràn, ẹ jọ̀wọ́ ara yín sílẹ̀ fún wa; kí ẹ sì darapọ̀ mọ́ wa kí ẹ sì ní òye nípa àwọn iṣẹ́ òkùnkùn wa, kí ẹ sì di arákùnrin wa kí ẹ̀yin ó lè rí bí àwa ti rí—kĩ ṣe ẹrú wa, ṣùgbọ́n arákùnrin wa àti alábãpín nínú gbogbo ohun-ìní wa. Sì kíyèsĩ, mo búra pẹ̀lú rẹ, bí ẹ̀yin o bá ṣe eleyĩ, pẹ̀lú ìbúra, a kò ní pa yín run; ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá ní ṣe eleyĩ, èmi búra fún ọ pẹ̀lú ìbúra, pé ní oṣù èyítí nbọ̀ èmì yíò pàṣẹ fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi kí wọn ó sọ̀ka lẹ̀ wá láti kọlũ ọ́, nwọn kò sì ní dáwọ́ dúró, nwọn kò sì ní dá ẹnìkẹ́ni sí, ṣùgbọ́n wọn yíò pa yín, wọn yíò sì mú kí idà wọn ó ṣubú lù yín àní títí ẹ̀yin ó fi di aláìsí. Sì kíyèsĩ, èmi ni Gídíánhì; èmi sì ni bãlẹ̀, ẹgbẹ́ òkùnkùn Gádíátónì yĩ; ẹgbẹ́ àti iṣẹ́ èyítí èmi mọ̀ wípé ó dára; nwọ́n sìjẹ́ ti ìgbà àtijọ́ tí nwọ́n sì ti fií lé wa lọ́wọ́. Èmi sì kọ èpístélì yĩ sí ọ, Lákónéúsì, èmi sì ní ìrètí pé ẹ̀yin yíò fi àwọn ilẹ̀ yín àti àwọn ohun-ìní yín lé wa lọ́wọ́, láìsí ìtàjẹ̀sílẹ̀, kí àwọn ènìyàn mi yĩ ó lè gba ẹ̀tọ́ àti ìjọba wọn padà, àwọn ẹni ti wọn ti yapa kúrò lára yín nítorí ìwà búburú yín láti fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n nínú ìjọba, bí ẹ̀yin kò bá sì ṣe èyí, èmi yíò gbẹ̀san. Ẹmí ni Gídíánhì. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Lákónéúsì gba èpístélì yĩ, ẹnu yã lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ìgboyà tí Gídíánhì ní láti fi agbára bẽrè fún níní ilẹ̀ àwọn ará Nífáì ní ìní, àti láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nã àti láti gbẹ̀san àwọn tí a kò ṣẹ̀, bíkòṣe pé àwọn ni ó ṣẹ ara wọn nípa yíyapa kúrò lọ sí ọ́dọ̀ àwọn ọlọ́ṣà oníwà búburú àti oníríra ènìyàn nnì. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, Lákónéúsì yĩ, tí íṣe bãlẹ̀, jẹ́ ènìyàn tí ó tọ́, àwọn ìbẽrè àti ìkìlọ̀ ọlọ́ṣà kò sì lè dẹ́rùbà á; nítorínã kò fetísílẹ̀ sí èpístélì Gídíánhì, bãlẹ̀ àwọn ọlọ́ṣà nã, ṣùgbọ́n ó mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó kígbe pe Olúwa fún agbára fún àkokò nã tí àwọn ọlọ́ṣà nã yíò sọ̀kalẹ̀ wá láti kọlù wọ́n. Bẹ̃ni, ó fi ìkéde ránṣẹ́ sí ãrín àwọn ènìyàn gbogbo, pé kí wọn ó kó àwọn obìnrin wọn jọ, àti àwọn ọmọ wọn, àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn àti àwọn agbo ẹran wọn, àti gbogbo ohun-ìní wọn, bíkòṣe ilẹ̀ wọn nikan, sí ojúkan. Ó sì mú kí wọn ó mọ́ àwọn odi yí wọn ká, kí agbára nwọn ó sì pọ̀ púpọ̀. Ó sì mú kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, àti ti àwọn ará Nífáì àti ti àwọn ará Lámánì, tàbí tí gbogbo àwọn tí a kà mọ́ àwọn ará Nífáì, kí a fi wọ́n ṣe ẹ̀ṣọ́ yíká kiri láti ṣọ́ wọn, àti láti dãbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà nã ní ọ̀sán àti ní òru. Bẹ̃ni, ó wí fún wọn pé: Bí Olúwa ti wà lãyè, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá ronúpìwàdà gbogbo àìṣedẽdé yín, tí ẹ sì kígbe pe Olúwa, kò sí ọ̀nà tí a fi lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì nnì. Títóbi àti ìyàlẹ́nu ni àwọn ọ̀rọ̀ àti àsọtẹ́lẹ̀ Lákónéúsì sì jẹ́ tóbẹ̃ ti wọn mú kí ẹ̀rù kí ó bá gbogbo àwọn ènìyàn nã; tí wọ́n sì sa gbogbo agbára wọn láti ṣe gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ Lákónéúsì. Ó sì ṣe tí Lákónéúsì yan àwọn olórí-ogun àgbà lórí gbogbo awọn egbẹ́ ọmọ-ogun Nífáì, láti darí wọn ní àkokò tí àwọn ọlọ́ṣà nã yíò sọ̀kalẹ̀ wá láti inú aginjù láti kọlù wọ́n. Nísisìyí a yàn èyítí ó ga jùlọ nínú gbogbo àwọn olórí-ogun àgbà nã àti olùdarí-àgbà gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, orúkọ rẹ̀ sì ni Gídgídónì. Nísisìyí ojẹ àṣà lãrín gbogbo àwọn ará Nífáì láti yàn gẹ́gẹ́bí olórí-ogun àgbà wọn, (àfi ní àkokò ìwà búburú wọn) ẹnití ó ní ẹ̀mí ìfihàn àti ìsọtẹ́lẹ̀; nítorínã, Gídgídónì yĩ jẹ́ wòlĩ ńlá lãrín wọn, gẹ́gẹ́bí onidajọ àgbà nã ti jẹ́. Nísisìyí àwọn èniyàn nã wí fún Gídgídónì pé: Gbàdúrà sí Olúwa, kí o sì jẹ́ kí àwa ó lọ sí órí àwọn òkè gíga àti sínú aginjù, kí àwa ó lè kọ lu àwọn ọlọ́ṣà nã kí a sì pa wọ́n run nínú ilẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n Gídgídónì wí fún wọn pé: Olúwa kà á lẽwọ̀;nítorítí bí àwa bá gòkè lọ láti kọlù wọ́n Olúwa yíò fi wá lé wọn lọ́wọ́; nítorínã àwa yíò múrasílẹ̀ ní ãrín àwọn ilẹ̀ wa, àwa yíò sì kó gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa jọ, àwa kò sì ní lọ láti kọlù wọ́n, ṣùgbọ́n àwa yíò dúró de ìgbà tí wọn yíò wá kọlù wá; nítorínã bí Olúwa ṣe wà lãyè, bí àwa bá ṣe èyí òun yíò fi wọ́n lé wa lọ́wọ́. Ó sì ṣe ní ọdún kẹtàdínlógún, nígbati ọdún nã fẹ́rẹ̀ parí, ìkéde Lákónéúsì ti kọjá lọ jákè-jádò orí ilẹ̀ nã, tí wọ́n sì ti kó àwọn ẹṣin wọn, àti àwọn kẹ̀kẹ́-ogun wọn, àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, àti gbogbo ọ̀wọ́ ẹran wọn, àti gbogbo agbo ẹran wọn, àti àwọn ọkà wọn, àti gbogbo ohun-ìní wọn, tí wọ́n sì kọjá lọ ní ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àti ẹgbẹ̃gbẹ̀rún mẹ́wã, títí gbogbo wọn fi kọjá lọ sí ibití a ti yàn fún wọn láti kó ara wọn jọ sí, láti dãbò bò ara wọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Ilẹ̀ tí a sì ti yàn nã sì ni ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti ilẹ̀ tí ó wà lãrín ilẹ̀ Sarahẹ́múlà àti ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, bẹ̃ni, títí dé ãlà-ilẹ̀ tí ó wà lãrín ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀ àti ilẹ̀ Ibi-Ahoro. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ̀rún nlá ènìyàn ni a sì npè ní ará Nífáì, tí wọ́n sì kó ara wọn jọ pọ sínú ilẹ̀ yĩ. Nísisìyí Lákónéúsì sì mú kí wọn ó kó ara wọn jọ sínú ilẹ̀ ti apá gúsù nítorí ègún nlá tí ó wà lórí ilẹ̀ ti apá àríwá. Wọ́n sì dãbò bò ara wọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n sì ngbé inú ilẹ̀ kanṣoṣo, àti ní ìsọ̀kán, wọn sì bẹ̀rù àwọn ọ̀rọ̀ ti Lákónéúsì ti sọ, tóbẹ̃ tí wọ́n ronúpìwàdà gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn; wọ́n sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wọn, pé kí ó gbà wọ́n ní àkokò tí àwọn ọ̀tá wọn yíò sọ̀kalẹ̀ wá dojú ogun kọ wọ́n. Wọ́n sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi nítorí àwọn ọ̀tá wọn. Gídgídónì sì mú kí wọ́n rọ àwọn ohun-ìjà ogun lónírũrú, pé kí wọn ó sì wà ní ipò agbára pẹ̀lú àwọn ìhámọ́ra, àti pẹ̀lú àwọn oun ìdábò bò wọn, àti pẹ̀lú àwọn asà, ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀. 4 Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ará Nífáì ṣẹ́gun àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì—Wọ́n pa Gídíánhì, ẹnití ó rọ́pò rẹ̀, Sẹ́mnáríhà, ni wọn sì so rọ̀—Àwọn ará Nífáì yin Olúwa fún ìṣẹ́gun tí wọ́n ní. Ní ìwọ̀n ọdún 19 sí 22 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Ó sì ṣe ní ìparí ọdún kejìdínlógún tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ọlọ́ṣà nnì ti múrasílẹ̀ fún ogun, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sọ̀kalẹ̀ wá tí wọ́n sì tú jáde láti orí àwọn òkè nã, àti jáde láti inú àwọn òkè gíga, àti aginjù, àti àwọn ibi gíga wọn, àti àwọn ibi ìkọ̀kọ̀ wọn tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí mú àwọn ilẹ̀ nã ní ìní, àti àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ apá gúsù àti àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ apá àríwá, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí mú gbogbo àwọn ilẹ̀ tí àwọn ará Nífáì ti kọ̀ sílẹ̀ ní ìní, àti àwọn ìlú nlá tí wọ́n ti sọ di ahoro. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, kò sí àwọn ẹranko búburú tàbí ẹran ọdẹ nínú àwọn ilẹ̀ nnì èyítí àwọn ará Nífáì ti kọ̀ sílẹ̀, kò sì sí ẹran ọdẹ fún àwọn ọlọ́ṣà nã àfi nínú aginjù. Àwọn ọlọ́ṣà nã kò sì lè wà lãyè àfi nínú aginjù, nítorí àìsíoúnjẹ; nítorí tí àwọn ará Nífáì ti sọ ilẹ̀ wọn di ahoro, wọ́n sì ti kó àwọn ọ̀wọ ẹran wọn àti àwọn agbo ẹran wọn àti gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kán. Nítorínã, kò sí ãyè fún àwọn ọlọ́ṣà nã láti ṣe ìkógun àti láti rí oúnjẹ, àfi bí wọ́n bá jáde wá láti dojúkọ àwọn ará Nífáì ní ìjà; àwọn ará Nífáì sì wà ní àkójọpọ̀ kanṣoṣo, nítorípé wọ́n pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, tí wọ́n sì ti fi àwọn ohun-ìpèsè pamọ́ fún ara wọn, àti ẹṣin àti ẹran ọ̀sin àti ọ̀wọ́ ẹran ní onírũrú, kí wọn ó lè jẹ́ fún ìwọ̀n ọdún méje, nínú àkokò èyítí wọ́n ní ìrètí pé àwọn yíò pa àwọn ọlọ́ṣà nã run kúrò lórí ilẹ̀ nã; bayĩ sì ni ọdún kejìdínlógún kọjá lọ. Ó sì ṣe ní ọdún kọkàndínlógún tí Gídíánhì rí i pé ó yẹ fún òun láti jáde lọ láti gbé ogun ìjà ti àwọn ará Nífáì, nítorítí kò sí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà jẹ àfi kí wọn ó kógun àti jalè àti kí wọn ó pànìyàn. Wọn kò sì jẹ́ tàn ká orí ilẹ̀ nã láti gbin irúgbìn, ní ìbẹ̀rù pé àwọn ará Nífáì yíò kọlũ wọ́n tí wọn ó sì pa wọ́n; nítorínã ni Gídíánhì pàṣẹ fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ pé nínú ọdún yĩ ni kí wọn ó lọ láti gbé ogun ìjà ti àwọn ará Nífáì. Ó sì ṣe ti wọ́n jáde lọ láti jà; ó sì jẹ́ nínú oṣù kẹfà; ẹ sì kíyèsĩ, ọjọ́ nla ti ó sì ní ẹ̀rù, ni ọjọ́ nã nínú èyítí wọn jáde lọ láti jà; wọ́n sì wọ ẹ̀wù gẹ́gẹ́bí àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n sì lọ́ awọ-ọ̀dọ́-àgùtàn mọ́ ìbàdí, wọ́n sì rẹ ara wọn nínú ẹ̀jẹ̀, wọ́n sì fá orí wọn, wọ́n sì fi ìbòrí-ogun bò orí wọ́n; àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Gídíánhì nã sì pọ̀ wọn sì ní ẹ̀rù, nítorí ìhámọ́ra wọn àti nítorítí wọn ti rẹ ara wọn nínú ẹ̀jẹ̀. Ó sì ṣe ti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, nígbàtí wọ́n rí i bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Gídíánhì ti rí, wọ́n wó lulẹ̀, wọ́n sì kígbe pe Olúwa Ọlọ́run wọn, pé kí ó dá wọn sí kí ó sì gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Gídíánhì rí èyí wọ́n bẹ̀rẹ̀sí kígbe pẹ̀lú ohùn rara, nítorí ayọ̀ wọn, nítorítí wọ́n rò pé àwọn ará Nífáì nã ti ṣubú fún ẹ̀rù nítorí ẹ̀rù àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn. Ṣùgbọ́n nínú èyí ni ìrètí wọn ṣákì, nítorítí àwọn ará Nífáì kò bẹ̀rù wọn; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run wọn tí nwọn sì nbẹ̃ fún ãbò rẹ̀; nítorínã, nígbàtí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Gídíánhì sáré síwájú láti pàdé wọn; bẹ̃ni, nínú agbára Olúwa ni wọ́n pàdé wọn. Ìjà nã sì bẹ̀rẹ̀ nínú oṣù kẹfà, ìjà nã sì pọ̀ ó sì ní ẹ̀rù, bẹ̃ni, ìpànìyàn rẹ̀ sì pọ̀ ó sì ní ẹ̀rù, tóbẹ̃ tí kò sí irú ìpànìyàn tí ó pọ̀ báyĩ rí lãrín àwọn ènìyàn Léhì láti ìgbàtí ó ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Àti l’áìṣírò àwọn ìhàlẹ̀mọ́ àti ìbúra ti Gídíánhì ti ṣe, ẹ kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì lù wọ́n, tóbẹ̃ tí wọ́n fi sá padà kúrò níwájú wọn. Ó sì ṣe tí Gídgídónì pàṣẹ pé kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ó sá tẹlé wọn títí dé òpin ilẹ̀ aginjù nã, àti pé kí wọn ó má dá ẹnikẹ́ni tí ó bá bọ́ sí ọwọ́ wọ́n bí wọ́n ti nlọ sí; báyĩ ni wọn sì sá tele wọn àti tí wọ́n sì pa wọ́n, títídé ibi òpin ilẹ̀ aginjù, àní títí wọ́n fi pa àṣẹ Gídgídónì mọ́ tán. Ó sì ṣe tí nwọ́n sá tẹ̀lé Gídíánhì, ẹnití ó ti dúró tí ó sì jà pẹ̀lú ìgboyà, bí ó ti nsálọ; àti nítorípé ó ti rẹ̃ nítorí ìjà púpọ̀ tí ó ti jà wọ́n bã wọ́n sì pã. Báyĩ sì ni ìgbésí ayé Gídíánhì ọlọ́ṣà nnì dópin. Ó sì ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì sì padà sí ibi àbò wọn. Ó sì ṣe tí ọdún kọkàndínlógún yí kọjá lọ, àwọn ọlọ́ṣà nã kò sì tún padà wá bá wọn jà; bẹ̃ sì ni wọn kò tún padà wá ní àkokò ogún ọdún. Àti ní ọdún kọkànlélógún wọn kò wá láti bá wọn jà, ṣùgbọ́n wọn gba ọ̀nà púpọ̀ yọ sí wọn láti ká àwọn ènìyàn Nífáì nã mọ́; nítorítí wọ́n rò wípé bí àwọn bá dínà mọ́ àwọn ènìyàn Nífáì nã kúrò lórí ilẹ̀ wọn, tí wọ́n sì ká wọn mọ́ ní gbogbo ọ̀nà, àti pé bí wọ́n bá dínà mọ́ wọn mọ́ gbogbo àwọn ohun tí nlọ ní àyíká wọn pé wọn ó mú kí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn lé wọn lọ́wọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú wọn. Nísisìyí wọ́n ti yan olórí míràn lé ara wọn lórí, ẹnití orúkọ rẹ̀ íṣe Sẹ́mnáríhà; nítorínã ni ó fi jẹ́ wípé Sẹ́mnáríhà ni ẹnití ó mú kí ìdótì yĩ ó wá. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èyí jẹ́ ohun ànfãní fún àwọn ará Nífáì; nítorítí ó jẹ́ ohun tí kò ṣeéṣe fún àwọn ọlọ́ṣà nã láti ká àwọn ará Nífáì nã mọ́ pẹ́ títí láti lè pa wọ́n lára, nítorí ìpèsè púpọ̀ tí wọ́n ti kó pamọ́. Àti nítorí ìpèsè tí kò tó lãrín àwọn ọlọ́ṣà nã; nítorí ẹ kíyèsĩ, wọn kò ní ohunkóhun bíkòṣe ẹran fún jíjẹ, ẹran èyítí wọn nrí mú nínú aginjù. Ó sì ṣe tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ nã sì ṣọ̀wọ́n nínú aginjù tóbẹ̃ tí àwọn ọlọ́ṣà nã fẹ́rẹ̀ parun fún ebi. Àwọn ará Nífáì sì njáde lọ ní ọ̀sán àti ní òru, tí wọ́n sì nkọlù àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, tí wọ́n sì npa wọn ní ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àti ní ẹgbẹ̃gbẹ̀rún mẹ́wã-mẹ́wã. Báyĩ ni ó sì jẹ́ ìfẹ́ inú àwọn ènìyàn Sẹ́mnáríhà láti fà sẹ́hìn nínú ète wọn, nítorí ìparun nlá tí ó ti kọlũ wọ́n ní òru àti ní ọ̀sán. Ó sì ṣe tí Sẹ́mnáríhà sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé kí wọn ó fà sẹ́hìn nínú ìdótì nã, kí wọn ó sì kọjá lọ sí ibití ó jìnà réré nínú ilẹ̀ nã ní apá àríwá. Àti n í s i s ì y í , n í t o r í t í Gídgídónì ti ní ìfura sí ète wọn, tí ó sì mọ̀ nípa àìlera tí wọn ní nítorí àìsí oúnjẹ fún wọn, àti ìpakúpa tí wọ́n ti pa wọ́n, nítorínã ni ó ṣe rán àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jáde ní òru, tí ó sì sé ọ̀nà mọ́ wọn láti má lè sá padà, tí ó sì fi àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ dínà mọ́ wọn lati má lè sá padà. Èyí ni wọ́n sì ṣe ní òru, tí wọ́n sì kọjá àwọn ọlọ́ṣà nã, tí ó fi jẹ́ wípé ní ọjọ́ kejì, nígbàtí àwọn ọlọ́ṣà nã bẹ̀rẹ̀ ìrìn wọn, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì bá wọn pàdé ní iwájú àti ní ẹ̀hìn. Wọ́n sì sé ọ̀nà mọ́ àwọn ọlọ́ṣà tí ó wà ní apá gúsù pẹ̀lú láti má lè sá padà. Gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí ni wọ́n sì ṣe nípasẹ̀ àṣẹ Gídgídónì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ̃gbẹ̀rún wọn ni ó sì jọ̀wọ́ ara wọn sílẹ̀ ní ẹrú fún àwọn ará Nífáì, àwọn tí ó kù ni a sì pa. Olórí wọn, Sẹ́mnáríhà, ni wọn mú tí wọ́n sì soó rọ̀ kọ́ igi, bẹ̃ni, àní kọ́ orí rẹ̀ títí ó fi kú. Nígbàtí wọ́n sì ti so ó rọ̀ títí ó fi kú nwọn gé igi nã lulẹ̀ wọ́n sì kígbe ní ohùn rara, wípé: Kí Olúwa kí ó pa àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ nínú òdodo àti nínú ọkàn mímọ́, kí wọn ó lè mú kí a ké lulẹ̀ gbogbo àwọn tí yíò lépa láti pa wọ́n nítorí agbára àti ẹgbẹ́ òkùnkùn, àní gẹ́gẹ́bí a ti ké ọkùnrin yì í lulẹ̀. Nwọ́n sì yọ̀ wọn sì tún kígbe pẹ̀lú ohùn kanṣoṣo, wípé: Kí Ọlọ́run Ábráhámù, àti Ọlọ́run Ísãkì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù, ó dãbò bò àwọn ènìyàn yĩ nínú òdodo, níwọ̀n ìgbà tí wọn yíò bá ké pe orúkọ Ọlọ́run wọn fún ìdãbò bò. Ó sì ṣe tí wọ́n gbé ohùn sókè ní ọkanṣoṣo, ní orin kíkọ, àti ní fífi ìyìn fún Ọlọ́run wọn fún ohun nlá èyítí ó ti ṣe fún wọn, ní pípa wọ́n mọ́ kúrò nínú ìṣubú sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Bẹ̃ni, wọ́n sì kígbe wípé: Hòsánnà sí Ọlọ́run Ẹnití-Ó-Gá-Jùlọ. Nwọ́n sì tún kígbe wípé: Ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè, Ọlọ́run Ẹnití-Ó-Gá-Jùlọ. Ọkan wọn sì kún fún ayọ̀, títí omije púpọ̀ fi jáde lójú wọn, nítorí dídára ńlá Ọlọ́run ní gbígbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n sì mọ̀ pé nítorí ìrònúpìwàdà wọn àti ìwà-ìrẹ̀lẹ̀ wọn ni Olúwa ṣe gbà wọ́n kúrò nínú ìparun àìlópin. 5 Àwọn ará Nífáì ronúpìwàdà wọn sì kọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn sílẹ̀—Mọ́mọ́nì kọ ìtàn nípa àwọn ènìyàn rẹ̀ ó sì kéde ọ̀rọ̀ nã tí ó wà títí ayé fún wọn—A ó kó Ísráẹ́lì jọ kúrò nínú ipò ìfọ́nká rẹ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́. Ní ìwọ̀n ọdún 22 sí 26 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, kò sí ẹ̀mí alãyè kan lãrín àwọn ènìyàn Nífáì tí ó ní àìdánilójú bí ó ti kéré tó nípa àwọn ọ̀rọ̀ gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ tí ó ti sọ̀rọ̀; nítorítí wọ́n mọ̀ wípé ó di dandan pé kí wọn ó di mímúṣẹ. Wọ́n sì mọ̀ pé ó tọ̀nà pé Krístì ti dé, nítorí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì èyítí a ti fún wọn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ; àti nítorí àwọn ohun nnì èyítí ó ti di mímúṣẹ wọ́n mọ̀ pé ó di dandan pé ohun gbogbo níláti di mímúṣẹ ní ìbámu pẹ̀lú èyítí àwọn wòlĩ ti sọ. Nítorínã ni wọn kọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn sílẹ̀, àti àwọn ohun ìríra wọn, àti àwọn ìwà àgbèrè wọn, tí wọ́n sì nsin Ọlọ́run tọkàn tọkàn tọ̀sán-tòru. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n ti kó gbogbo àwọn ọlọ́ṣà nã lẹ́rú, tóbẹ̃ tí kò sí èyíkéyi tí ó sálọ tí a kò pa, wọn sì kó àwọn ẹrú wọn nã sínú túbú, wọ́n sì mú kí a wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí wọn; gbogbo àwọn tí ó bá sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti tí wọ́n sì bá wọn dá májẹ̀mú pé àwọn kò ní pànìyàn mọ́ ni wọ́n tú sílẹ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí wọn kò bá wọn dá májẹ̀mú, àti tí wọn sì tẹ̀síwájú lati ni ìwà ìpànìyàn ní ìkọ̀kọ̀ nínú ọkan wọn, bẹ̃ni,gbogbo àwọn tí wọ́n rí tí wọn nmí ẽmí ìdẹ́rùbani mọ́ àwọn arákùnrin wọn ni wọ́n dálẹ́bi tí wọ́n sì fìyàjẹ ní ìbámu pẹ̀lú òfin. Bàyĩ ni wọn sì fi òpin sí gbogbo awọn ẹgbẹ́ ìkọ̀kọ̀, búburú, ati ìríra nnì, nínú èyí tí ìkà ṣíṣe púpọ̀ wa, àti tí wọn nṣe ìpànìyàn púpọ̀púpọ̀. Báyĩ sì ni ọdún kejìlélógún ti kọjá lọ, àti ọdún kẹtàlélógún pẹ̀lú, àti ọdún kẹrìnlélógún, àti ìkárúndínlọ́gbọ̀n; àti báyĩ ni ọdún marúndínlọ́gbọ̀n ti kọjá lọ. Àwọn ohun tí ó pọ̀ sì ti ṣẹlẹ̀ èyítí, ní ojú àwọn ènìyàn kan, ó jẹ́ ohun nlá àti ìyanilẹ́ni; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a kò lè kọ gbogbo wọn sínú ìwé yĩ; bẹ̃ni, ìwé yĩ kò lè gba ìdá kan nínú ọgọ́rún àwọn ohun tí nwọ́n ṣe lãrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn nínú ìwọ̀n ọdún márúndínlọ́gbọ̀n. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ àwọn àkọsílẹ̀ wà èyítí o ni àwọn ìṣe àwọn ènìyàn yĩ nínú; Nífáì sì kọ nípa ìṣe nã ní kúkúrú ṣùgbọ́n ní òtítọ́. Nítorínã ni èmi fi kọ àkọsílẹ̀ mi nípa àwọn ohun yĩ ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ Nífáì, èyítí a gbẹ́ sí orí àwọn àwo àkọsílẹ̀ tí a pè ní àwo Nífáì. Ẹ sì kíyèsĩ, èmi kọ àkọsílẹ̀ nã lé orí àwọn àwo èyítí èmi fi ọwọ́ ara mi ṣe. Ẹ sì kíyèsĩ, Mọ́mọ́nì ní orúkọ mi, nítorítí a fi orúkọ ilẹ̀ ti Mọ́mọ́nì pè mí, ilẹ̀ nínú èyítí Álmà dá ìjọ onígbàgbọ́ sílẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn nã, bẹ̃ni, ìjọ onígbàgbọ́ èkínní tí a da sílẹ̀ lãrín wọn lẹ́hìn ìwà ìrékọjá wọn. Ẹ kíyèsĩ, ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run ni èmi íṣe. Òun ni ó pè mí láti kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀, kí wọn ó lè ní ìyè títí ayé. Ó sì ti di ohun tí ó tọ̀nà kí èmi, ní ìbámú pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àdúrà àwọn tí ó ti kọjá lọ, àwọn tí ó jẹ́ àwọn ẹni mímọ́, lè gbà gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn, kí ó kọ àkọsílẹ̀ nípa àwọn ohun yĩ èyítí wọn ti ṣe— Bẹ̃ni, àkọsílẹ̀ kékeré nípa èyítí ó ti ṣẹlẹ̀ láti àkokò tí Léhì ti fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀, àní títí dé àkokò yĩ. Nítorínã ni èmi ṣe kọ àkọsílẹ̀ mi bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ìṣe èyítí àwọn tí ó ṣãju mi ti kọ, títí di ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà tèmi; Nígbànã ni èmi ṣe àkọsílẹ̀ nípa àwọn ohun tí èmi ti fi ojú ara mi rí. Èmi sì mọ̀ pé àkọsílẹ̀ tí èmi ṣe jẹ́ àkọsílẹ̀ tí ó tọ́ tí ó sì jẹ́ òtítọ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃ àwọn ohun púpọ̀ ni ó wà tí a kò lè kọ nítorí èdè wa. Àti nísisìyí èmi mú ọ̀rọ̀ mi wá sí ópin, èyítí íṣe nípa ara mi, mo sì tẹ̀síwájú láti kọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ kí èmi ó tó dé ayé. Mọ́mọ́nì ni èmi íṣe, mo sì jẹ́ àtẹ̀lé Léhì lódodo. Mo ní ìdí láti fi ìbùkún fún Ọlọ́run mi àti Olùgbàlà mi Jésù Krístì, pé ó mú àwọn bàbá wa jáde kúrò nínú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, (kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ̀ nípa rẹ̀ àfi òun tìkararẹ̀ àti àwọn tí ó mú jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã) àti nítorítí ó ti fún èmi àti àwọn ènìyàn mi ní ìmọ̀ tí ó pọ̀ púpọ̀ sí ìgbàlà ọkàn wa. Dájúdájú ó ti bùkún fún ìdílé Jákọ́bù, ó sì ti ṣãnú fún irú-ọmọ Jósẹ́fù. Àti tóbẹ̃ bí àwọn àtẹ̀lé Léhì ti pa òfin rẹ̀ mọ́ ni ó ṣe bùkúnfún wọn tí ó sì mú wọn ṣe rere gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bẹ̃ni, dájúdájú òun yíò sì tún mú ìyókù nínú irú-ọmọ Jósẹ́fù sínú ìmọ̀ nípa Olúwa Ọlọ́run wọn. Àti bí ó ti dájú pé Olúwa wà lãyè, ni yíò kó wọn jọ láti igun mẹ́rẹ̀rin ayé gbogbo àwọn ìyókù nínú irú-ọmọ Jákọ́bù, tí ó ti fọ́nkákiri lórí gbogbo orí ilẹ̀ ayé. Bí ó sì ti bá gbogbo ìdílé Jákọ́bù dá májẹ̀mú, bẹ̃ nã ni májẹ̀mú nã èyítí ó ti bá ìdílé Jákọ́bù dá yíò di mìmúṣẹ ní àkokò tirẹ, títí dé ìmúpadà bọ́ sípò gbogbo ìdílé Jákọ́bù sí ti ìmọ̀ nípa májẹ̀mú tí ó ti bá wọn dá. Nígbànã ni wọn yíò sì mọ́ Olùràpadà wọn, ẹnití íṣe Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run; nígbànã ni a o sì kó wọn jọ láti igun mẹ́rẹ̀rin ayé sínú àwọn ilẹ̀ tiwọn, láti ibití wọn ti fọ́n wọn ká sí; bẹ̃ni, bí Olúwa ti wà lãyè, bẹ̃ni yíò rí. Àmín. 6 Àwọn ará Nífáì ní ìlọsíwájú—Ìgbéraga, ọrọ̀, àti ẹlẹ́yà-mẹ̀yà ẹgbẹ́ yọ jáde—Ìjọ pínyà pẹ̀lú ìyapa—Sátánì darí àwọn ènìyàn nã sí ìṣọ̀tẹ̀ gbangba—Àwọn wòlĩ púpọ̀ wãsù ìrònúpìwàdà a sì pa wọ́n—Àwọn tí ó pa wọn dìtẹ̀ láti gba ìjọba. Ní ìwọ̀n ọdún 26–30 nínú ọjọ́ Olúwa. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn ará Nífáì gbogbo sì padà lọ sí órí ilẹ̀ wọn nínú ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n, olúkúlukù, pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀ àti agbo ẹran rẹ̀, àwọn ẹṣin rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀, àti ohun gbogbo tí íṣe tiwọn. Ó sì ṣe tí wọn kò tĩ jẹ gbogbo àwọn ohun ìpèsè wọn tán; nítorínã ni wọ́n fi kó gbogbo ohun tí wọn kò tĩ jẹ pẹ̀lú wọn, gbogbo àwọn ọkà wọn lónírurú, àti wúrà wọn, àti fàdákà wọn, àti àwọn nkan ojúlówó wọn, wọ́n sì padà sí órí ilẹ̀ wọn àti sí àwọn ohun ìní wọn, àti ní àríwá àti ní gúsù, àti ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá àti ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá gúsù. Wọ́n sì fi ilẹ̀ fún àwọn ọlọ́ṣà nnì tí wọ́n ti bá wọn dá májẹ̀mú láti wà ní álãfíà lórí ilẹ̀ nã, tí wọ́n ní ìfẹ́ láti wà bí àwọn ará Lámánì, àwọn ilẹ̀, gẹ́gẹ́bí wọn ti pọ̀ tó, kí wọn ó lè ní ohun tí wọn yíò fi gbé ilé ayé nípa iṣẹ́ ṣíṣe wọn; báyĩ sì ni wọ́n fi àlãfíà lélẹ̀ lórí ilẹ̀ nã. Wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀sí ní ìlọsíwájú àti láti pọ̀ síi ní agbara; ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n àti ìkẹtàdínlọ́gbọ̀n sì kọjá, ètò nlá sì wà lórí ilẹ̀ nã; wọn sì ṣe àwọn òfin wọn ní ọ̀nà ìṣòtítọ́ àti àìṣègbè. Àti nísisìyí kò sí ohunkóhun nínú gbogbo ilẹ̀ nã tí yíò ṣe ìdíwọ́ fún àwọn ènìyàn nã láti ní ìlọsíwájú títí, àfi bí wọ́n bá ṣubú sínú ìwà ìrékọja. Àti nísisìyí Gídgídónì, àti Lákónéúsì, onidajọ, àti àwọn wọnnì tí a ti yàn gẹ́gẹ́bí olórí ni wọ́n fi àlãfíà nlá yĩ lélẹ̀ ní ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí àwọn ìlú nlá púpọ̀ di títúnkọ́, tí àwọn ìlú àtijọ́ sì di títúnṣe. Àwọn ọ̀nà òpópó púpọ̀ sì di kíkọ́, àti àwọn ọ̀nà púpọ̀ ni a là, èyítí ó lọ láti ìlú-nlá dé ìlú-nlá, àti láti ilẹ̀ dé ilẹ̀, àti láti ibìkan dé ibìkan. Báyĩ sì ni ọdún kéjìdínlọ́gbọ̀n kọjá, àwọn ènìyàn nã sì ní àlãfíà títí. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe ní ọdún kọkàndínlọ́gbọ̀n tí àríyànjiyàn bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín àwọn ènìyàn nã; tí àwọn kan gbé ara wọn sókè ní ìgbéraga àti lílérí nítorípé wọn ní ọrọ̀ púpọ̀, bẹ̃ni, àní, títí fi de ṣíṣe inúnibíni púpọ̀púpọ̀; Nítorí àwọn oníṣòwò púpọ̀ wà lórí ilẹ̀ nã, àti àwọn amòfin púpọ̀púpọ̀ àti olórí púpọ̀púpọ̀. Àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìyàtọ̀ sí ara wọn nípa ipò tí ènìyàn wà; gẹ́gẹ́bí ọrọ̀ wọ́n ti pọ̀ tó àti gẹ́gẹ́bí wọ́n ti ní ànfàní ẹ̀kọ́ kíkọ́ tó; bẹ̃ni, àwọn kan wà ní ipò aláìmọ̀ nítorí àìní wọn, àwọn míràn sì gba ẹ̀kọ́ kíkọ́ púpọ̀púpọ̀ nítorí ọ̀pọ̀ ọrọ̀ wọn. Àwọn kan gbé ọkàn wọn sókè ní ìgbéraga, àwọn míràn sì rẹ ara wọn sílẹ̀ púpọ̀púpọ̀; àwọn kan sì fi ẽbú san fún ẽbú, tí àwọn míràn yíò sì gba ẽbú àti inúnibíni àti onírurú ìpọ́njú, tí wọn kìyo sí yíjú padà láti dá ẽbú padà, ṣùgbọ́n wọn rẹ ara wọn sílẹ̀ wọ́n sì wà ní ipò ìrònúpìwàdà níwájú Ọlọ́run. Báyĩ sì ni àidọ́gba nlá wà lórí gbogbo ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run nã sì bẹ̀rẹ̀sí pín sí ọ̀nà púpọ̀; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run nã fi pín sí ọ̀nà púpọ̀ ni gbogbo ilẹ̀ nã nígbàtí odi ọgbọ̀n ọdún, àfi ní ãrín àwọn ará Lámánì díẹ̀ tí a ti yípadà sí ìgbàgbọ́ òtítọ́; tí wọn kò sì ní yísẹ̀padà kúrò nínú rẹ̀, nítorítí wọ́n dúróṣinṣin, wọ́n sì wà gbọin-gbọin, àti láìyísẹ̀padà, tí wọn sì ní ìfẹ́ tọkàntara láti pa òfin Olúwa mọ́. Nísisìyí ohun t í ó mú àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã wá ni èyí—Sátánì ní agbára nla, láti fi rú àwọn ènìyàn sókè láti ṣe onírũrú àìṣedẽdé, àti láti mú wọn di agbéraga, tí ó ntàn wọ́n láti máa wá agbára, àti àṣẹ, àti ọrọ̀, àti àwọn ohun asán ayé yĩ. Báyĩ sì ni Sátánì darí ọkàn àwọn ènìyàn nã láti ṣe onírurú àìṣedẽdé; nítorínã ni wọ́n ṣe rí àlãfíà fún ọdún díẹ̀. Àti báyĩ, ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ̀n ọdún—lẹhin ti a ti fi àwọn ènìyàn nã sílẹ̀ fún ìwọ̀n ọjọ́ pípẹ́ fún àdánwò èṣù láti darí wọn lọ sí ibikíbi tí ó bá wũ, àti láti ṣe àìṣedẽdé èyíkéyi tí ó bá wũ kí wọn ṣe—àti báyĩ ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ̀n ọdún yĩ, wọn wà ní ipò ìwà búburú tí ó lẹ́rù. Nísisìyí wọn kò dẹ́ṣẹ̀ láìmọ̀, nítorítí wọ́n mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún wọn, nítorítí a ti fi kọ́ wọn; nítorínã ni wọ́n ṣe mọ̣́mọ̀ ṣe ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Àti nísisìyí àkokò Lákónéúsì ní íṣe, ọmọkunrin Lákónéúsì, nítorítí Lákónéúsì ni ó wà lórí ìtẹ́-ìdájọ́ rọ́pò bàbá rẹ̀ ó sì ṣe ìjọba lórí àwọn ènìyàn nã ní ọdún nnì. Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀sí gba ìmísí láti ọ̀run tí a sì rán wọ́n jáde, tí wọ́n sì dúró lãrín àwọn ènìyàn nã ní gbogbo ilẹ̀ nã, tí wọn nwãsù ti wọn si njẹ́rĩ pẹ̀lú igboya nipa àwọn ẹṣẹ àti àwọn àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã, tí wọ́n sì njẹ́rĩ fún wọn nípa ìràpadà nã èyítí Olúwa yíò ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀, tàbí ní ọ̀nà míràn, àjĩnde Krístì; wọ́n sì jẹ́rĩ pẹ̀lú ìgboyà nípa ikú àti ìjìyà rẹ̀. Nísisìyí àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn nã ni ó bínú gidigidi nítorí àwọn tí ó jẹ́rĩ nípa àwọn ohun wọ̀nyí; àwọn tí ó sì bínú jùlọ ni àwọn adájọ́ àgbà, àti àwọn tí wọn ti fi igbakan rí jẹ́ olórí àlùfã àti amòfin; bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí íṣe amòfin ni ó bínú sí àwọn tí ó jẹ́rĩ nípa àwọn ohun wọ̀nyí. Nísisìyí kò sí amòfin kankan tàbí adájọ́ tàbí olórí àlùfã tí ó ní agbára láti dájọ́ ikú fún ẹnìkẹ́ni láìjẹ́ wípé bãlẹ̀ ilẹ̀ nã fi ọwọ́ sí ìdájọ́ nã. Nísisìyí àwọn púpọ̀ nínú àwọn tí ó jẹ́rĩ nípa àwọn ohun ti Krístì tí wọ́n jẹ́rĩ pẹ̀lú ìgboyà, ni àwọn adájọ́ mú tí wọn sì pa ní ìkọ̀kọ̀, tí pípa tí wọ́n pa wọ́n kò sì di mímọ̀ fún bãlẹ̀ ilẹ̀ nã títí di ẹ̀hìn tí wọ́n ti pa wọ́n. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èyí tako àwọn òfin ilẹ̀ nã, pé wọn yíò pa ẹnìkẹ́ni bíkòṣepé wọ́n ní àṣẹ láti ọwọ́ bãlẹ̀ ilẹ̀ nã— Nítorínã ni ẹ̀sun fi wá sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, sí ọ̀dọ̀ bãlẹ̀ ilẹ̀ nã, nípa àwọn adájọ́ yĩ tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún àwọn wòlĩ Olúwa, ní ìtakò òfin. Nísisìyí ó sì ṣe tí a mú wọn tí a sì mú wọ́n wá sí iwájú adajọ́, fún ìdájọ́ lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú òfin èyítí àwọn ènìyàn nã ti fi lélẹ̀. Nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn adájọ́ nnì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rẹ́ àti ìbátan; àti àwọn yókù, bẹ̃ni, àní tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo àwọn amòfin àti àwọn olórí àlùfã, ni wọn sì kó ara wọn jọ, tí wọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ìbátan àwọn adájọ́ nnì tí a fẹ́ ṣe ìdájọ́ fún ní ìbámu pẹ̀lú òfin. Nwọ́n sì bá ara wọn dá májẹ̀mú, bẹ̃ni, àní wọ inú májẹ̀mú èyítí àwọn ẹni ìgbà nnì fi lélẹ̀, májẹ̀mú èyítí ẹ̀ṣù fi lélẹ̀, tí ó sì nṣe ìpínfúnni rẹ̀, láti gbìmọ̀ lòdìsí gbogbo òdodo. Nítorínã ni wọ́n ṣe gbìmọ̀ lòdìsí àwọn ènìyàn Olúwa, tí wọn sì dá májẹ̀mú láti pa wọ́n run, àti láti gbá àwọn tí wọ́n jẹ̀bi ìpànìyàn kúrò lọ́wọ́ àìṣègbè, èyítí nwọ́n ti ṣetán láti ṣe ìpínfúnni rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òfin. Nwọ́n sì ṣe ìpèníjà sí òfin àti ẹ̀tọ́ orílẹ̀-èdè wọn; wọ́n sì bá ara wọn dá majẹ̀mú láti pa bãlẹ̀ nã run, àti láti fi ọba sí orí ilẹ̀ nã, kí ilẹ̀ nã ó má lè wà ní ipò òmìnirà ṣùgbọ́n kí wọn ó wà lábẹ́ òfin àwọn ọba. 7 Wọ́n pá adájọ́ àgbà, wọ́n pa ìjọba rẹ̀ run, àwọn ènìyàn nã sì pín sí àwọn ẹ̀yà—Jákọ́bù, aṣòdìsí-Krístì kan, di ọba fún ẹgbẹ́ òkùnkùn kan—Nífáì nwãsù ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Krístì—Àwọn ángẹ́lì nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún un lójojúmọ́, ó sì jí arákùnrin rẹ̀ dìde kúrò nínú ipò òkú—Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ronúpìwàdà tí a sì rì wọn bọmi. Ní ìwọ̀n ọdún 30–33 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èmi yíò fi hàn nyín pé wọn kò fi ọba jẹ lórí ilẹ̀ nã; ṣùgbọ́n nínú ọdún kannã yĩ, bẹ̃ni, ọgbọ̀n ọdún, wọ́n pã run lórí ìtẹ́ ìdájọ́, bẹ̃ni, wọ́n pa adájọ agbà ilẹ̀ nã. Àwọn ènìyàn nã sì wà ní ìpinyà ní ọ̀kan sí òmíràn; wọ́n sì ya ara wọn sọ́tọ̀ sí ẹ̀yà-ẹ̀yà, olúkúlukù gẹ́gẹ́bí ìdílé rẹ̀ àti ìbátan rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́; báyĩ ni wọ́n sì pa ìjọba ilẹ̀ nã run. Gbogbo ẹ̀yà kọ̣́kan sì yan olórí tàbí olùdarí lórí wọn; báyĩ ni wọ́n sì di ẹ̀yà àti olórí àwọn ẹ̀yà-ẹ̀yà. Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, kò sí ẹnìkẹ́ni lãrín wọn tí kò ní ìdílé tí ó pọ̀ àti ìbátan púpọ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́; nítorínã ni àwọn ẹ̀yà-ẹ̀yà wọn di púpọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nísisìyí wọ́n ṣe gbogbo eleyĩ, kò sì tĩ sí ogun lãrín wọn; gbogbo àwọn àìṣedẽdé yĩ dé bá àwọn ènìyàn nã nítorípé wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn fún agbára Sátánì. Wọ́n pa àwọn ìlànà ìjọba nã run, nítorí ẹgbẹ́ òkùnkùn àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn ìbátan àwọn wọnnì tí ó pa àwọn wòlĩ. Nwọ́n sì dá ìjà nlá sílẹ̀ ní ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn nã tí wọ́n jẹ́ olódodo jùlọ ti fẹ́rẹ̀ di ènìyàn búburú; bẹ̃ni, àwọn olódodo díẹ̀ ni ó wà lãrín wọn. Báyĩ ọdun mẹ́fà kò ì tĩ kọjá lọ tí púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn nã ti yí kúrò nínú ìwà òdodo wọn, bí ajá tí ó padà sí ẽbì rẹ̀, tàbí ẹlẹ́dẹ̀ sínú ìpàfọ̀ nínú ẹrẹ̀ rẹ̀. Nísisìyí ẹgbẹ́ òkùnkùn yĩ, tí ó ti mú àìṣedẽdé nlá bá àwọn ènìyàn nã, sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì fi ọkùnrin kan ṣe olórí wọn ẹnití wọn npè ní Jákọ́bù; Wọn sì pè é ní ọba wọn; nítorínã ó di ọba lórí ẹgbẹ́ búburú yĩ; ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olórí tí ó sọ̀rọ̀ tako àwọn wòlĩ tí ó jẹ́rĩ nípa Jésù. Ó sì ṣe tí wọn kò pọ̀ níye tó àwọn ẹ̀yà-ẹ̀yà àwọn ènìyàn nã, tí wọ́n parapọ̀ àfi ní ti pé àwọn olórí wọn ni ó fi àwọn òfin wọ́n lélẹ̀, olúkúlukù gẹ́gẹ́bí ẹ̀yà tirẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọ́n jẹ́ ọ̀tá; l’áìṣírò wọn kĩ ṣe olódodo ènìyàn, síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n parapọ̀ nínú ìkórira àwọn tí ó ti bá ara wọn dá májẹ̀mú láti pa ìjọba nã run. Nítorínã, Jákọ́bù, nítorítí ó ríi pé àwọn ọ̀tá wọn pọ̀ jù wọ́n lọ, nítorítí òun ni ọba àwọn ẹgbẹ́ nã, nítorínã ó ṣe pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé kí wọn ó sálọ sí apá àríwá ilẹ̀ nã níbití ó jìnà jù, kí wọn ó sì fi ìjọba lélẹ̀ fún ara wọn níbẹ̀, títí àwọn olùyapa yíò fi darapọ̀ mọ́ wọn, (nítorítí ó tàn wọ́n pé àwọn olùyapa púpọ̀ yíò wà), tí wọn yíò fi lágbára tó láti dojúkọ àwọn ẹ̀yà-ẹ̀yà àwọn ènìyàn nã; wọ́n sì ṣe bẹ̃. Ìrìn-àjò wọn nã sì yá tóbẹ̃ tí kò sí ohun tí ó lè dí wọn lọ́wọ́ tàbí fà wọ́n sẹ́hìn títí wọ́n fi kọjá lọ kúrò ní ìkáwọ́ àwọn ènìyàn nã. Báyĩ sì ni ọgbọ̀n ọdún parí; àti báyĩ sì ni ìṣe àwọn ènìyàn Nífáì. Ó sì ṣe ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n tí wọ́n pín ara wọn sí ẹ̀yà-ẹ̀yà, olúkúlukù gẹ́gẹ́bí ìdílé rẹ̀, ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọ́n ti jọ ní àdéhùn pè wọn kò ní bá ara wọn jagun; ṣùgbọ́n wọn kò darapọ̀ ní ti àwọn òfin wọn, àti bí wọ́n ṣe nṣe ìjọba wọn, nítorí wọ́n fi wọ́n lélẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọkàn àwọn tí wọn jẹ olórí wọn àti àwọn adarí wọn. Ṣugbọn wọn fi àwọn òfin tí ó múná púpọ̀púpọ̀ lélẹ̀ pé kí ẹ̀yà kan ó máṣe ré òmíràn kọjá, tóbẹ̃ tí wọ́n fi ní àlãfíà níwọ̀n díẹ̀ ní ilẹ̀ nã; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ọkàn wọn yí kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn, tí wọ́n sì sọ àwọn wòlĩ ní òkúta tí wọ́n sì lé wọn kúrò lãrín wọn. Ó sì ṣe tí Nífáì—nítorítí àwọn ángẹ́lì ti bẹ̃ wò àti ohùnOlúwa pẹ̀lú, nítorínã nítorítí ó ti rí àwọn ángẹ́lì, àti nítorípé ó jẹ́ ẹlẹ́rĩ, àti nítorítí ó ní agbára tí a ti fi fún un kí ó lè mọ̀ nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ Krístì, àti nítorípé ó jẹ́ ẹlẹ́rĩ sí yíyára kúrò nínú òdodo sínú ìwà búburú àti ìwà ìríra wọn; Nítorínã, nítorítí ó banújẹ́ nítorí ọkàn wọ́n tí ó le àti ọkàn wọn tí o fọ́jú—ó kọjá lọ lãrín wọn nínú ọdún kannã, ó sì bẹ̀rẹ̀sí jẹ́rĩ pẹ̀lú ìgboyà, sí ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì Olúwa. Ó sì jíṣẹ́ nípa ohun púpọ̀ fún wọn; a kò sì lè kọ gbogbo wọn sílẹ̀, díẹ̀ nínú wọn kò sí tó láti kọ, nítorínã a kò kọ wọn sínú ìwé yĩ. Nífáì sì jíṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú agbára àti àṣẹ nlá. Ó sì ṣe tí wọ́n bínú síi, àní nítorípé ó ní agbára ti o tobi jù wọ́n lọ, nítorítí kò ṣeéṣe fún wọ́n láti má gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jésù Krístì Olúwa pọ̀ tóbẹ̃ tí àwọn ángẹ́lì njíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún un lójojúmọ́. Àti ní orúkọ Jésù ni ó lé àwọn èṣù àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde; àti pãpã ó jí arákùnrin rẹ̀ dìde kúrò nínú ipò òkú, lẹ́hìn tí àwọn ènìyàn nã sọọ́ ní òkúta tí ó sì ti kú. Àwọn ènìyàn nã sì ríi, ó sì ṣe ojú wọn, wọ́n sì bínú síi nítorí agbára rẹ̀; ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu síi, lójú àwọn ènìyàn nã, ní órúkọ Jésù. Ó sì se tí ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n kọjá lọ,tí ó sì jẹ́ wípé àwọn díẹ̀ ni ó yí ọkàn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa; sùgbọ́n gbogbo àwọn tí a yí lọkan padà ni ó fi hàn fún àwọn ènìyàn nã pé agbára àti Ẹ̀mí Ọlọ́run ti bẹ̀ wọ́n wò, èyítí ó wà nínú Jésù Krístì, ẹnití wọ́n gbàgbọ́. Gbogbo àwọn tí a sì lé àwọn èṣù jáde kúrò nínú wọn, tí wọ́n sì gba ìwòsàn nínú àwọn àìsàn wọn àti àwọn àìlera wọn, ni wọ́n fihàn lọ́bọ fún àwọn ènìyàn nã pé Èmí Ọlọ́run ti ṣiṣẹ́ lórí wọn, tí a sì ti wò wọ́n sàn; wọ́n sì fi àwọn àmì hàn pẹ̀lú tí wọ́n sì ṣe àwọn isẹ́ ìyanu díẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn nã. Báyĩ sì ni ọdún kejìlélọ́gọ̀n kọjá lọ pẹ̀lú. Nífáì sì kígbe sí àwọn ènìyàn nã ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ketàlélọ́gbọ̀n; ó sì wãsù ìrònúpìwàdà sí wọn àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Nísisìyí èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó rántí pẹ̀lú pé kò sí ẹnìkẹ́ni tí a mú wá sí ìrònúpìwàdà tí a kò rìbọmi pẹ̀lú omi. Nítorínã ni Nífáì yan àwọn ọkùnrin sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yĩ, pé gbogbo àwọn tí ó bá tọ̀ wọ́n wá ni wọ́n ní láti rìbọmi pẹ̀lú omi, èyí ni ó sì dúró gẹ́gẹ́bí ẹlẹ́rĩ àti ìjẹ́rií níwájú Ọlọ́run, àti sí àwọn ènìyàn nã, pé wọ́n ti ronúpìwàdà tí wọ́n sì ti gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àwọn tí ó rìbọmi sí ìrònúpìwàdà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yĩ sì pọ̀; báyĩ sì ni púpọ̀ nínú ọdún nã ṣe kọjá lọ. 8 Èfũfùlíle, ile riri, iná, ìjì, àti àwọn ìrúkèrúdò ayé jẹ́rĩ sí ìyà kíkàn mọ́ àgbélèbú Krístì—Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni ó parun—Òkùnkùn bò ilẹ̀ nã fùn ọjọ́ mẹ́tà—Àwọn tí ó wàlãyè npohùn réré ẹkún nítorí ìpín wọn. Ní ìwọ̀n ọdún 33–34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe wípé gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ wa, àwá sì mọ̀ pè àkọsílẹ̀ wa jẹ́ òtítọ́, nítorítí ẹ kíyèsĩ, ẹnití o tọ́ ni ẹnití ó pa àkọsílẹ̀ nã mọ́—nítorítí ó se ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu ní orúkọ Jésù; kò sì sí ẹnìkẹ́ni tí ó lè se iṣẹ́ ìyanu kan ní orúkọ Jésù bí kò se pé a wẹ̃ mọ́ pátápátá kúrò nínú àìṣedẽdé rẹ̀— Àti nísisìyí ó sì ṣe, bí kò bá sí àṣìṣe láti ọwọ́ ọkùnrin yĩ nípa ìṣírò ìgbà wa, ọgbọ̀n ọdún ó lé mẹ́ta ti kọjá lọ; Àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí fojúsọ́nà pẹ̀lú ìtara fún àmì nã èyítí wòlĩ Sámúẹ́lì, ará Lámánì nì ti kéde, bẹ̃ni, fún àkókò nã tí òkùnkùn yíò bò ojú ilẹ̀ nã ní ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta. Iyè meji àti àríyànjiyàn nlá sì bẹ̀rẹ̀ sí wà lãrín àwọn ènìyàn nã, l’áìṣírò a ti fún wọn ní àwọn àmì tí ó pọ̀. Ó sì ṣe ní ọdún kẹrinlélọ́gbọ̀n, ní osù kíni, ní ọjọ́ kẹ́rin osù nã, ìjì nlá kan rú sókè, irú èyítí a kò rí rí ní gbogbo ilẹ̀ nã. Èfũfù nlá kan ti o dẹ́rùbani sì tún wà; àrá búburú sì sán, tóbẹ̃ tí ó mi gbogbo ayé bí èyítí yìó là sí méjì. Àwọn mọ̀nàmọ́ná tí ó mọ́lẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ sì wà, irú èyítí a kò rí rí ní gbogbo ilẹ̀ nã. Ìlú-nlá Sarahẹ́múlà sí jóná. Ìlú-nlá Mórónì sì jìn sínú ibú omi, àwọn olùgbé inú rẹ̀ sì rì sínú omi. Ilẹ̀ sì di gbígbé sókè ká orí ìlú-nlá Móróníhà, tí a fi ní òkè gíga nlá kan dípò ìlú-nlá nã. Ìparun nlá èyítí ó burú sì wà ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù. Sùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ìparun nla tí ó sì burú síi sì wà ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá; nítorí ẹ kíyèsĩ, gbogbo orí ilẹ̀ nã ni ó yípadà, nítorí ìjì àti àwọn ẹ̀fũfù líle nã, sísán àrá àti kíkọ mọ̀nàmọ́ná, àti mimì tìtì gbogbo ilẹ̀ nã; Gbogbo àwọn ọ̀nà òpópó ni ó sì fọ́ sí wẹ́wẹ́, àwọn ọ̀nà tí ó tẹ́jú sì di bíbàjẹ́, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibití ó tẹ́jú di págun-pàgun. Àwọn ìlú nlá olókìkí rì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì jóná, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì mì tí àwọn ilé inú wọn fi wó lulẹ̀, tí àwọn tí ngbé inú wọn sì kú, tí gbogbo ibẹ̀ sì di ahoro. Àwọn ìlú kan sì wà tí a dásí; ṣùgbọ́n tí àdánù inú wọn pọ̀ jùlọ, àti ọpọlọlopọ ni o wà nínú wọn ti wọn sì kú. Àwọn kan ni èfùfulile sì gbé lọ; tí ẹnì kan kò sì mọ́ ibití wọ́n lọ, bíkòse pé wọ́n mọ̀ pé ó gbé wọn lọ. Báyĩ sì ni orí ilẹ̀ ayé gbogbo wà ní àìbójúmu nítorí àwọn èfũfù nlá, àti sísán àrá, àti kíkọ mọ̀nàmọ́ná, àti mimì tìtì ilẹ̀ nã. Sì kíyèsĩ, àwọn àpáta di lílà sí méjì; wọn sì di fífọ́ sí orí ilẹ̀ ayé gbogbo, tóbẹ̃ tí a sì rí wọn ní àkúfọ́, àti ní sísán, àti ní fífọ́ sí wẹ́wẹ́, lórí gbogbo ilẹ̀ ayé. Ò sì ṣe nígbàtí àwọn sísán àrá, àti kíkọ mọ̀nàmọ́ná, àti èfũfù líle, àti ìjì àti mimì tìtì ilẹ̀ nã dáwọ́dúró—nítorítí ẹ kíyèsĩ, wọ́n wà fún ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta; àwọn ènìyàn kan sì sọ pé àkokò nã ju èyí; bíótilẹ̀ríbẹ̃, gbogbo àwọn ohun ìṣẹ̀lẹ̀ nlá búburú yĩ ni ó ṣẹ̀ ní ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta—nígbànã ẹ sì kíyèsĩ, òkùnkùn bò ojú ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí òkùnkùn biribiri bò gbogbo ojú ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí àwọn olùgbé inú ìlú nã tí kò ì kú sì mọ̀ ìkùukù òkùnkùn; Kò sì lè sí ìmọ́lẹ̀, nítorí òkùnkùn nã, tàbí iná fìtílà, tàbí ètúfù iná; tàbí kí iná kankan ó lè tàn pẹ̀lú àwọn igi wọn dáradára tí ó gbẹ lọ́pọ̀lọpọ̀, tí ó fi jẹ́ wípé kò sí ìmọ́lẹ̀ kankan rárá; Kò sì sí ìmọ́lẹ̀ kankan tí wọ́n rí, tàbí iná, tàbí ìmọ́lẹ̀ báìbáì, tàbí oòrùn, tàbí òṣùpá, tàbí àwọn ìràwọ̀, nítorítí àwọn ikúkuú tí ó wà lójú ilẹ̀ nã pọ̀ tóbẹ̃. Ó sì ṣe tí ó wà fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta tí wọn kò rí ìmọ́lẹ̀; ìkẹ́dùn ọkàn nlá àti híhu àti ẹkún sísun sì wà lãrín àwọn ènìyàn nã títí; bẹ̃ni, títóbi sì ni ìkérora àwọn ènìyàn nã, nítorí òkùnkùn nã àti ìparun nlá èyítí ó ti dé bá wọn. Ní ibìkan ni a sì tí gbọ́ tí wọn nkígbe, tí wọ́n nwípé: A! àwa ìbá sì ti ronúpìwàdà ṣãjú ọjọ́ nlá èyítí ó burú yĩ, nígbànã ni àwọn arákùnrin wa ìbá wà ní dídásí, tí iná kì bá ti jó wọn pa nínú ìlú nlá títóbi nnì, Sarahẹ́múlà. Ní ibòmíràn a sì gbọ́ tí wọn nkígbe tí wọn nṣọ̀fọ̀, tí wọn nwípé: A! àwa ìbá sì ti ronúpìwàdà ṣãjú ọjọ́ nlá èyítí ó burú yĩ, tí àwa ìbá má ti pa àwọn wòlĩ, ti a sì sọ wọ́n lókuta, tí a sì lé wọn jáde; nígbànã ni àwọn ìyá wa àti àwọn ọmọbìnrin wa tí ó lẹ́wà, àti àwọn ọmọ wa ìbá ti wà ní dídásí, tí wọn kì bá ti di bíbòmọ́lẹ̀ nínú ìlú-nlá títóbi nnì, Móróníhà. Báyĩ sì ni híhu àwọn ènìyàn nã pọ̀ tí ó sì burú. 9 Nínú òkùnkùn nã, ohùn Krístì kéde nípa ìparun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti àwọn ìlú-nlá nítorí ìwà búburú wọn—Ó tun kéde nípa bí òun ti wà bí Ọlọ́run, ó sọọ́ ní gbangba pé òfin Mósè ti di ìmúṣẹ, ó sì pe gbogbo ènìyàn láti wá sí ọ́dọ̀ òun kí wọn ó sì rí ìgbàlà. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Ó sì ṣe tí a gbọ́ ohùn kan lãrín gbogbo àwọn olùgbé inú ayé, lórí gbogbo ilẹ̀ yĩ, tí ó nkígbe wípé: Ègbé, ègbé, ègbé ni fún àwọn ènìyàn yĩ, ègbé ni fún àwọn ènìyàn tí ńgbé inú gbogbo ayé àfi bí wọ́n bá ronúpìwàdà; nítorítí èṣù nrẹ̃rín, àwọn ángẹ́lì rẹ̀ sì nyọ̀, nítorí àwọn tí a pa nínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí ó lẹ́wà nínú àwọn ènìyàn mi; tí ó sì jẹ́ nítorí ìwà àìṣedẽdé wọn àti ìwà ìríra wọn ni wọn ṣe kú! Ẹ kíyèsĩ, ìlú-nlá Sarahẹ́múlà títóbi nnì ni èmi ti fi iná jó, àti àwọn olùgbé inú rẹ̀. Ẹ sì kíyèsĩ, ìlú-nlá Mórónì títóbi nnì ni èmi ti mú kí ó rì nínú ibú òkun, àti àwọn olùgbé inú rẹ̀ ni èmi mú kí wọn ó rì. Ẹ sì kíyèsĩ, ìlú nlá Móróníhà títóbi nnì ni èmi ti bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú erupẹ, àti àwọn olùgbé inú rẹ̀, láti mú àwọn ìwà àìṣedẽdé wọn àti ìwà ẽrí wọn pamọ́ kúrò níwájú mi, kí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlĩ àti ti àwọn ènìyàn mímọ́ nnì ó má bã tọ̀ mí wá mọ́ ni ìtakò sí wọn. Ẹ sì kíyèsĩ, ìlú nlá Gílgálì ni èmi ti mú kí ó rì, àwọn olùgbéinú rẹ̀ ni èmi sì mú kí a bò mọ́lẹ̀ nínú ilẹ̀ jínjìn; Bẹ̃ni, àti ìlú nlá Oníhà àti àwọn olùgbé inú rẹ̀, àti ìlú nlá Mókúmì àti àwọn olùgbé inú rẹ̀, àti ìlú nlá Jerúsálẹ́mù àti àwọn olùgbé inú rẹ; omi ni ẹmí sì fi dípò wọn, láti mú àwọn ìwà búburú àti ìwà ẽrí wọn pamọ́ kúrò níwájú mi, kí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlĩ àti àwọn ènìyàn mímọ́ nnì ó má bã gòkè wá sí ọ́dọ̀ mi mọ́ ní ìtakò sí wọn. Ẹ sì kíyèsĩ, ìlú nlá Gádíándì, àti ìlú nlá Gádíómnáhì, àti ìlú nlá Jákọ́bù, àti ìlú nlá Gímgímnò, gbogbo àwọn wọ̀nyí ni èmi ti mú kí wọn ó rì, tí èmi sì fi àwọn òkè àti àfonífojì sí ipò wọn; àti àwọn olùgbé inú wọn ni èmi sì bò mọ́lẹ̀ nínú ilẹ̀ jíjìn, láti mú àwọn ìwà búburú àti àwọn ìwà ẽrí wọn pamọ́ kúrò níwájú mi, kí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlĩ àti àwọn ènìyàn mímọ́ nnì ó má bã gòkè wá sí ọ́dọ̀ mi mọ́ ní ìtakò sí wọn. Ẹ sì kíyèsĩ, ìlú nlá Jákọ́bùgátì, èyítí àwọn ènìyàn ọba Jákọ́bù a máa gbé inú rẹ̀, ni èmi ti mú kí a jó niná nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àwọn ìwà búburú wọn, èyítí ó tayọ gbogbo ìwà búburú ayé gbogbo, nítorí àwọn ìpànìyàn ní ìkọ̀kọ̀ àti awọn ẹgbẹ́ òkùnkùn wọn; nítorítí àwọn ni ó pa àlãfíà àwọn ènìyàn mi run àti ijọba ilẹ̀ nã; nítorínã ni èmi ṣe mú kí a jó wọn níná, láti pa wọn run kúrò níwájú mi, kí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlĩ àti àwọn ènìyàn mímọ́ nnì ó má bã gòkè wá sí ọ́dọ̀ mi mọ́ ni ìtakò sí wọn. Ẹ sì kíyèsĩ, ìlú nlá Lámánì, àti ìlú nlá Jọ́ṣì, àti ìlú nlá Gadì, àti ìlú nlá Kíṣkúmẹ́nì, ni èmi ti mú kí a jó níná, àti àwọn olùgbé inú wọn, nítorí ìwà búburú wọn ní lílé àwọn wòlĩ jáde, àti sísọ lokuta àwọn tí èmi rán láti sọ nípa ìwà búburú àti ìwà ẽrí wọn fún wọn. Àti nítorípé wọ́n lé gbogbo wọn jáde, tí kò sì sí ẹnití ó jẹ́ olódodo lãrín wọn, èmi sọ iná kalẹ̀ mo sì pa wọ́n run, kí ìwà búburú àti ìwà ẽrí wọn ó lè pamọ́ kúrò níwájú mi, kí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlĩ àti àwọn ènìyàn mímọ́ tí èmi rán sí ãrin wọn ó má lè ké pè mí láti inú ilẹ̀ wá ní ìtakò sí wọn. Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìparun nlá ni èmi sì ti mú wá sí órí ilẹ̀ yĩ, àti sí órí àwọn ènìyàn yĩ, nítorí ìwà búburú wọn àti ìwà ẽrí wọn. A! gbogbo ẹ̀yin tí a dá sí nítorípé ẹ̀yin jẹ́ olódodo jù wọ́n lọ, ẹ̀yin kò ha ní padà sí ọ́dọ̀ mi nísisìyí, kí ẹ sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì yípadà, kí èmi ó lè wò yín sàn bí? Bẹ̃ni, lọ́tọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin yíò bá wá sí ọ́dọ̀ mi ẹ̀yin yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ kíyèsĩ, apá ãnú mi nã síi yín, ẹnikẹ́ni tí yíò bá sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun ni èmi yíò gbà; alábùkún-fún sì ni àwọn tí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi. Ẹ kíyèsĩ, èmi ni Jésù Krístì Ọmọ Ọlọ́run. Èmi ni ó dá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn. Èmi wà pẹ̀lú Bàbá láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Mo wà nínú Bàbá, Bàbá nã sì wà nínú mi; nínú mi sì ni Bàbá ti ṣe orúkọ rẹ̀ lógò. Mo tọ àwọn tèmi wa, àwọn tèmi kò s ì gbà mí. Àwọn ìwé-mímọ́ nípa bíbọ̀ mi sì di mìmúṣẹ. Gbogbo àwọn tí ó sì ti gbà mí, ni èmi ti fi fún láti di ọmọ Ọlọ́run; bẹ̃ nã sì ni èmi yíò fi fún gbogbo àwọn tí yíò gba orúkọ mi gbọ́, nítorí ẹ kíyèsĩ, nípasẹ̀ mi ni ìràpadà yíò wa, àti nínú mi ni a mú òfin Mósè ṣẹ. Èmi ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé. Èmi ni Álfà àti Òmégà, ìpilẹ̀sẹ̀ àti òpin. Ẹ̀yin kò sì ní rú ẹbọ ìtàjẹ̀sílẹ̀ sí mi mọ; bẹ̃ni, àwọn ọrẹ ẹbọ yín àti àwọn ọrẹ ẹbọ sísun yín yíò dópin, nítorí èmi kò ní tẹwọ́gba ọ̀kan nínú àwọn ọrẹ ẹbọ nyín tàbí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun yín. Ẹ̀yin yíò sì rú ẹbọ ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́ sí mi fún ọrẹ ẹbọ. Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì tọ̀ mí wá pẹ̀lú ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, òun ni èmi yíò rìbọmi pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, àní bí àwọn ará Lámánì, nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú mi ní ìgbà ìyílọ́kànpadà wọn, tí a sì rì wọn bọmi pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọ́n kò sì mọ̣́. Ẹ kíyèsĩ, èmi wá sínú ayé láti mú ìràpadà wá sínú ayé, láti gba ayé là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Nítorínã, ẹnìkẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà tí ó sì tọ̀ mí wá bí ọmọdé; òun ni èmi yíò gbà, nítorí ti irú rẹ̀ ni ìjọba Ọlọ́run. Ẹ kíyèsĩ, nitori irú rẹ̀ ni emí fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, èmi sì tún tí mú u padà; nítorínã, ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi ẹ̀yin ìkangun ayé, kí a sì gbà yín là. 10 Ìdákẹ́rọ́rọ́ wà lórí ilẹ̀ nã fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí—Ohùn Krístì ṣe ìlérí pé òun yíò ràdọ̀ bò àwọn ènìyàn rẹ̀ bí àgbébọ̀ tií ràdọ̀ bò àwọn ọmọ lábẹ́ apá rẹ̀—Àwọn tí ó se olódodo jùlọ nínú àwọn ènìyàn nã ni a ti dá sí. Ní ìwọ̀n ọdún 34–35 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ó sì ṣe tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ nã gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí wọ́n sì jẹ́rĩ síi. Lẹ́hìn sísọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ìdákẹ́rọ́rọ́ sì wà lórí ilẹ̀ nã fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí; Nítorítí ìyàlẹ́nu àwọn ènìyàn nã pọ̀ tóbẹ̃ t í wọn dẹ́kun ìpohùnréré ẹkún àti híhu fún àdánù wọn lórí àwọn ìbátan wọn tí ó ti kú; nítorínã ni ìdákẹ́rọ́rọ́ ṣe wà lórí gbogbo ilẹ̀ nã fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí. Ó sì ṣe tí ohùn kan tún tọ àwọn ènìyàn nã wá, gbogbo àwọn ènìyàn nã sì gbọ́; wọn sì jẹ́rĩ nípa rẹ̀, tí ó wípé: A! ẹ̀yin ènìyàn tĩ ṣe ti ìlú nlá tí ó ti subú wọ̀nyí; tĩ ṣe àtẹ̀lé Jákọ́bù, bẹ̃ni, tĩ ṣe ti ìdílé Isráẹ́lì, báwo ni èmi tií ràdọ̀ bò yín nígbà-kũgbà bí àgbébọ tií ràdọ̀ bò àwọn ọmọ lábẹ́ apá rẹ̀, tí èmi sì tọ́ nyín dàgbà. Àti síbẹ̀síbẹ̀, báwo ni èmi ìbá tún ti ràdọ̀ bò yín nígbà-kũgbà bí àgbébọ̀ tií ràdọ̀ bò àwọn ọmọ lábẹ́ apá rẹ̀, bẹ̃ni, A! ẹ̀yin ènìyàn ìdílé Isráẹ́lì, tí ó ti subú; bẹ̃ni, A! ẹ̀yin ènìyàn ìdílé Isráẹ́lì, ẹ̀yin ti ńgbé inú Jerúsálẹ́mù, àti ẹ̀yin tí ó ti subú; bẹ̃ni, báwo ni èmi ìbá tún ti ràdọ̀ bò yín nígbà-kũgbà bí àgbébọ̀ tií ràdọ̀ bò àwọn ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò sì fẹ́. A! ẹyin ìdílé Isráẹ́lì èyítí èmi ti dásí, báwo ni èmi ìbá ti ràdọ̀ bò yín nígbà-kũgbà bí àgbébọ̀tií ràdọ̀ bò àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, bí ẹ̀yin yíò bá ronúpìwàdà kí ẹ sì padà sí ọ̀dọ̀ mi tọkàn-tọkàn. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá ṣe bẹ̃, A! ẹyin idile Israẹli àwọn ibùgbé yín gbogbo ni yíò di ahoro títí di àkokò ìmúṣẹ májẹ̀mú tí èmi Olúwa bá àwọn bàbá yín dá. Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí àwọn ènìyàn nã ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ẹ kíyèsĩ, wọ́n bẹ̀rẹ̀sí sọkún wọn sì tún nhu nítorí ìpàdánù àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Ó sì ṣe tí ọjọ́ mẹ́ta nã kọjá lọ báyĩ. Òwúrọ̀ ni í sì í ṣe, òkùnkùn sì ká kúrò lórí ilẹ̀ nã, ilẹ̀ sì dáwọ́ mimì dúró, àwọn àpáta sì dáwọ́ lílà sí méjì dúró, àwọn ìkérora búburú sì dáwọ́ dúró, gbogbo àwọn ariwo ìrúkèrúdò sì dáwọ́ dúró. Ilẹ̀ sì tún lè papọ̀ mọ́ ara wọn tí ó sì dúró gbọingbọin; àwọn ìkẹ́dùn ọkàn, àti ẹkún sísun, àti ìpohùnréré ẹkún àwọn ènìyàn nã tí a dá sí tí ó sì wà lãyè sì dáwọ́ dúró; ìkẹ́dùn ọkàn wọn sì di ayọ̀, ìpohùnréré ẹkún wọn sì di ìyìn àti ọpẹ́ sí Jésù Krístì Olúwa, Olùràpadà wọn. Bãyĩ sì ni àwọn ọ̀rọ̀ ìwémímọ́ di mímúṣẹ èyítí a ti sọ láti ẹnu àwọn wòlĩ. Àwọn tí ó sì jẹ́ olódodo jùlọ nínú àwọn ènìyàn nã ni a gbàlà, àwọn sì ni ó gba àwọn wòlĩ tí wọ́n kò sì sọ wọ́n ní òkúta pa; àwọn sì ni àwọn tí kò ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ sílẹ̀, ni a dá sí— A sì dá wọn sí, a kò sì tẹ̀ wọ́n rì sínú ilẹ̀ àti kí a bò wọ́n mọ́lẹ̀; a kò sì rì wọ́n sínú ibú omi òkun; a kò sì jó wọn nínú iná, bẹ̃ ni a kò wó lù wọ́n kí a sì tẹ̀ wọ́n pa; a kò sì gbé wọn lọ nínú ìjì: bẹ̃ ni a kò bò wọ́n mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìkũkù ẽfín àti òkùnkùn. Àti nísisìyí, ẹnìkẹ́ni tí ó bá ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kí ó ní ìmọ̀ wọn; ẹnití ó ní àwọn ìwé-mímọ́, kí ó wá inú wọn, kí ó ríi kí ó sì ṣe àkíyèsí bí gbogbo àwọn ikú àti ìparun nípasẹ̀ iná, àti nípasẹ̀ ẽfín, àti nípasẹ̀ èfũfù nlá, nípasẹ̀ ìjì, àti nípasẹ̀ ìṣísílẹ̀ ilẹ̀ láti gbe wọn mì, àti gbogbo ohun wọ̀nyí kò bá já sí mímúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ púpọ̀ nínú àwọn wòlĩ mímọ́. Ẹ kíyèsĩ mo wí fún yín, bẹ̃ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti jẹ́rĩ sí àwọn ohun wọ̀nyí ní àkókò bíbọ̀ Krístì, tí a sì pa wọ́n nítorípé wọ́n jẹ́rĩ sí àwọn ohun wọ̀nyí. Bẹ̃ni, wòlĩ Sénọ́sì jẹ́rĩ sí àwọn ohun wọ̀nyí, Sénọ́kì nã pẹ̀lú sọ nípa àwọn ohun wọ̀nyí, nítorípé wọ́n jẹ́rĩ ní pàtàkì nípa wa, tĩ ṣe ìyókù àwọn irú-ọmọ wọn. Ẹ kíyèsĩ, Jákọ́bù bàbá wa pẹ̀lú jẹ́rĩ nípa ìyókù irú-ọmọ Jósẹ́fù kan. Ẹ sì kíyèsĩ, àwa kò há íṣe ìyókù irú-ọmọ Jósẹ́fù kan bí? Àwọn ohun wọ̀nyí tí ó sì jẹ́rĩ nípa wa, njẹ́ a kò kọ wọ́n lé àwọn àwo idẹ nnì èyítí Léhì bàbá wa mú jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù bí? Ó sì ṣe ní òpin ọdún kẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, ẹ kíyèsĩ, èmi yíò fihàn yín pé àwọn ènìyàn Nífáì tí a dá sí, àti àwọn tí a ti pè ní ará Lámánì, tí a ti dá sí, sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúrere Krístì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún ni ó rọ̀ lé wọn lórí, tóbẹ̃ tí ó ṣe wípé ní kété lẹ́hìn ìgòkè Krístì lọ sí ọ̀run, ó fi ara rẹ̀ hàn sí wọn nítọ́tọ́— Tí ó fi ara rẹ̀ hàn sí wọ́n, tí ó sì nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn; a ó sì mu ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ wá lẹ́hìn èyí. Nítorínã fun àkókò yĩ, mo mú awọn ọ̀rọ̀ mi wá sí ópin ná. Jésù Krístì fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn ènìyàn Nífáì, bí àwọn ọpọ ènìyàn ṣe kó ara wọn jọ nínú ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, ó sì nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn; ní ọ̀nà yĩ ni ó sì fi ara rẹ̀ hàn sí wọn. Èyítí a kọ sí àwọn orí 11 títí ó fi dé 26 ní àkópọ̀. 11 Bàbá jẹ́rĩ nípa Àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀—Krístì fi ara hàn ó sì kéde nípa ètùtù rẹ̀—Àwọn ènìyàn nã fi ọwọ́ bà ojú ọgbẹ́ tí ó wà lọ́wọ́ àti lẹ́sẹ̀ àti ni ìhà rẹ̀—Nwọ́n kígbe Hòsánnà—Ó ṣe ìkọ́ni nípa ìṣe àti ìlànà ìrìbọmi—Ẹ̀mí ìjà jẹ́ ti ẹ̀ṣù—Ẹ̀kọ́ Krístì ni kí gbogbo ènìyàn ó gbàgbọ́ kí a sì rì wọ́n bọmi, kí wọn ó sì gba Ẹ̀mí Mímọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn kó ara wọn jọ, nínú àwọn ènìyàn Nífáì, yíká tẹ́mpìlì èyítí ó wà ní ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀; tí ẹnu sì nyà wọ́n tí wọ́n sì nṣe hà ní ọ̀kan pẹ̀lú òmíràn, tí wọ́n sì nfi ìyípadà nlá àti ìyanu èyítí ó ti ṣẹ̀lẹ̀ han ara wọn. Wọ́n sì nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú nípa Jésù Krístì yĩ, ẹnití a ti fúnni ní àmì nípa ikú rẹ̀. Ó sì ṣe bí wọ́n ti nsọ̀rọ̀ báyĩ pẹ̀lú ara wọn, wọ́n gbọ́ ohùn kan bí èyítí ó jáde wá láti ọ̀run; wọ́n sì wò yíká kiri, nítorí tí wọn kò ní òye nípa ohùn nã tí wọ́n gbọ́; ohùn líle kọ́ nií sì íṣe, bẹ̃ sì ni kĩ ṣe ohùn kíkan; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àti l’áìṣírò ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ó wọ̀ oókan àyà àwọn tí ó gbọ́ lọ, tóbẹ̃ tí kò sí ẹ̀yà ara wọn tí kò mú kí ó mì; bẹ̃ni, ó wọ inú ọkàn wọn lọ, ó sì mú kí ọkàn wọn ó gbiná. Ó sì ṣe tí wọ́n tún gbọ́ ohùn nã, tí kò sì yé wọn. Ní ìgbà kẹ́ta wọ́n tún gbọ́ ohùn nã, wọ́n sì ṣí etí wọn sílẹ̀ láti gbọ́ọ; wọ́n sì kọ ojú wọn sí ohùn nã, wọ́n sì tẹjúmọ́ ọ̀run níbití ohùn nã ti wá. Ẹ sì kíyèsĩ, ní ìgbà kẹ́ta, ohùn nã tí wọ́n gbọ́ yé wọn; ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsí Àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹnití inú mi dùn sí gidigidi, nínú ẹnití mo ti ṣe orúkọ mi lógo—ẹ gbọ́ tirẹ̀. Ó sì ṣe, bí òye sì ti yé wọn wọ́n sì tún gbé ojú wọn sókè sí ọ̀run; ẹ sì kíyèsĩ, wọ́n rí Ọkùnrin kan tí ó nsọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀run; ti a sì wọ̣́ ní aṣọ funfun kan; ó sì sọ̀kalẹ̀ wá ó sì dúró lãrín wọn; ojú gbogbo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã sì yí síi, wọn kò sì la ẹnu wọn, àní láti bá ara wọn sọ̀rọ̀, wọn kò sì mọ́ ohun tĩ ṣe nítorí tí wọ́n rò wípé ángẹ́lì ni ó farahàn wọ́n. Ó sì ṣe tí ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí wọn tí ó sì bá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀ wípé: Ẹ kíyèsĩ, èmi ni Jésù Krístì, ẹnití àwọn wòlĩ jẹ́rĩ sí pé yíò wá sínú ayé. Ẹ sì kíyèsĩ, èmi ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé; èmi sì ti mu nínú ago kíkòrò tí Bàbá fi fún mi, èmi sì ti ṣe Bàbá lógo nípa gbígbé ẹ̀ṣẹ̀ aráyé rù ara mi, nínú èyítí èmi gba ìfẹ́ Bàbá lãyè nínú ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni gbogbo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã ṣubú lulẹ̀; nítorítí wọ́n rántí pé a ti sọọ́ tẹ́lẹ̀ lãrín wọn wípé Krístì yíò fi ara rẹ̀ hàn fún wọn lẹ́hìn tí ó bá ti gòkè re ọ̀run. Ó sì ṣe tí Olúwa bá wọn sọ̀rọ̀ wípé: Ẹ dìde kí ẹ sì wá sí ọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin ó lè fi ọwọ́ yín sí ìhà mi, àti kí ẹ̀yin ó lè fi ọwọ́ yín sí ojú àpá ìṣó ni ọwọ́ àti ẹsẹ̀ mi, kí ẹ̀yin ó lè mọ̀ wípé èmi ni Ọlọ́run Ísráẹ́lì, àti Ọlọ́run gbogbo ayé, ti a sì pa fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. Ó sì ṣe tí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã jáde wá, wọ́n sì fi ọwọ́ wọn sí ìhà rẹ̀, wọ́n sì fi ọwọ́ wọn sí ojú àpá ìṣó ní ọwọ́ rẹ̀ àti ní ẹsẹ̀ rẹ̀; báyĩ ni wọ́n sì ṣe, tí wọ́n lọ ní ọ̀kọ̣́kan títí gbogbo wọn fi lọ, tí wọ́n sì ríi pẹ̀lú ojú ara wọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn kàn, tí wọ́n sì mọ̀ dájúdájú tí wọ́n sì jẹ́rĩ síi pé òun ni ẹnití àwọn wòlĩ kọ nípa rẹ̀, pé ó nbọ̀ wá. Nígbàtí gbogbo wọn sì ti jáde lọ tán tí wọ́n sì ti jẹ́rĩ síi fúnra wọn, wọ́n kígbe pẹ̀lú ohùn kan wípé: Hòsánnà! Ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run Ẹnití-Ó-Gá-Jùlọ! Wọ́n sì wólẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ Jésù, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un. Ó sì ṣe tí ó bá Nífáì sọ̀rọ̀ (nítorítí Nífáì wà lãrín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã) ó sì pàṣẹ fún un pé kí ó jáde wá. Nífáì sì dìde ó sì jáde lọ, ó sì wólẹ̀ níwájú Olúwa ó sì fi ẹnu ko ẹsẹ̀ rẹ̀. Olúwa sì pàṣẹ fún un pé kí ó dìde. Ó sì dìde ó sì dúró níwájú rẹ̀. Olúwa sì wí fún un pé: mo fi agbára fún ọ kí ìwọ ó ri àwọn ènìyàn yĩ bọmi nígbàtí èmi bá tún ti gòkè lọ sí ọ̀run. Olúwa sì tún pe àwọn míràn, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà bẹ̃; ó sì fi agbára láti ṣe ìrìbọmi fún wọn. Ó sì wí fún wọn pé: Ní ọ̀nà yĩ ni ẹ̀yin yíò ṣe ìrìbọmi; kí àríyànjiyàn ó má sì ṣe wà lãrín yín. Lóotọ́ ni mo wí fún yín, wípé ẹnìkẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ yín, tí ó sì nífẹ́ àti ṣe ìrìbọmi ní orúkọ mi, ní ọ̀nà yĩ ni ẹ̀yin yíò sì rì wọ́n bọmi—Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin yíò sọ̀kalẹ̀ lọ ẹ ó sì dúró nínú omi, ní orúkọ mi ni ẹ̀yin yíò sì rì wọn bọmi. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin yíò sọ, ẹ ó pe orúkọ wọn, ẹ ó wípé: Nítorítí mo ní àṣẹ láti ọwọ́ Jésù Krístì, mo rì ọ́ bọmi ní orúkọ Bàbá, àti ní ti Ọmọ, àti ní ti Ẹ̀mí Mímọ́, Àmin. Nígbànã ni ẹ̀yin ó tẹ̀ wọ́n rì bọ inú omi nã, tí wọn ó sì tún jáde kúrò nínú omi nã. Ní ọ̀nà yĩ ni ẹ̀yin yíò ṣe ìrìbọmi ní orúkọ mi; nítorí ẹ kíyèsĩ, lóotọ́ ni mo wí fún yín, wípé Bàbá, àti Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ ọ̀kan; èmi sì wà nínú Bàbá, Bàbá sì wà nínú mi, Bàbá àti èmi sì jẹ́ ọkan. Gẹ́gẹ́bí èmi sì ti pàṣẹ fún yín bẹ̃ni kí ẹ̀yin ó ṣe ìrìbọmi. Kí àríyànjiyàn ó má sì ṣe wà lãrín yín, bí ó ti wà ṣãjú àkokò yĩ; bẹ̃ni kí àríyànjiyàn ó má ṣe wà lãrín yín nípa àwọn ohun àfiyèsí tí ó wà nínú ẹ̀kọ́ mi, bí ó ti wà ṣãjú àkokò yĩ. Nítorí lóotọ́, lóotọ́ ni mo wí fún yín, ẹnití ó bá ní ẹ̀mí asọ̀ kĩ ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ti èṣù nií ṣe, ẹnití íṣe bàbá asọ̀, òun a sì máa rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè láti bá ara wọn jà pẹ̀lú ìbínú. Ẹ kíyèsĩ, èyí kĩ íṣe ẹ̀kọ́ mi, láti rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè pẹ̀lú ìbínú, ọ̀kan sí òmíràn; ṣùgbọ́n èyĩ ni ẹ̀kọ́ mi, pé kí a mú irú ohun wọnnì kúrò. Ẹ kíyèsĩ, lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, èmi yíò sọ nípa ẹ̀kọ́ mi fún yín. Èyí sì ni ẹ̀kọ́ mi, ó sì jẹ́ ẹ̀kọ́ èyítí Bàbá ti fi fún mi; èmi sì jẹ́ ẹ̀rí nípa Bàbá, Bàbá sì jẹ́ ẹ̀rí nípa mi, Ẹ̀mí Mímọ́ sì jẹ́ ẹ̀rí nípa Bàbá àti èmi; èmi sì jẹ́rĩ síi pé Bàbá pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo, láti ronúpìwàdà, kí wọn ó sì gbàgbọ́ nínú mi. Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì gbàgbọ́ nínú mi, tí a sì rì bọmi, òun ni a ó gbàlà; àwọn ni ẹnití yíò sì jogún ìjọba Ọlọ́run. Ẹnìkẹ́ni tí kò bá sì gbàgbọ́ nínú mi, tí a kò sì rì bọmi, ni yíò si jẹ́ ẹni ègbé. Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, pé èyí ni ẹ̀kọ́ mi, èmi sì jẹ́rĩ síi pé láti ọ̀dọ̀ Bàbá ni ó ti wá; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì gbàgbọ́ nínú mi, gbàgbọ́ nínú Bàbá pẹ̀lú; òun sì ni Bàbá yíò jẹ́rĩ nípa mi sí, nítorítí òun yíò bẹ̃ wò pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́. Báyĩ sì ni Bàbá yíò jẹ́rĩ nípa mi, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò sì jẹ́rĩ síi nípa Bàbá àti èmi; nítorí Bàbá, àti èmi, àti Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ ọ̀kan. Àti pẹ̀lú mo wí fún yín, ẹ níláti ronúpìwàdà, kí ẹ sì dàbí ọmọdé, kí a sì rì yin bọmi ní orúkọ mi, bíkòrí bẹ̃ ẹ̀yin kò lè rí àwọn ohun wọ̀nyí gbà rárá. Àti pẹ̀lú mo wí fún yín, ẹ níláti ronúpìwàdà, kí a sì rì yín bọmi ni órúkọ mi, kí ẹ sì dàbí ọmọdé, bí kò bá rí bẹ̃ ẹ̀yin kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run. Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, pé èyí ni ẹ̀kọ́ mi, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì kọ́lé lé èyí kọ́lé lé orí àpáta mi, ẹnu-ọ̀nà ọrun àpãdì kì yíò sì lè borí wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ju èyí tàbí tí ó dín in kù, tí ó sì pẽ ní ẹ̀kọ́ mi, òun kannã ni ó wá nípa ibi, a kò sì kọ́ọ lé orí àpáta mi; ṣùgbọ́n ó kọ́lé sí órí ìpilẹ̀ iyanrìn, àwọn ẹnu-ọ̀nà ọrun àpãdì sì ṣí sílẹ̀ láti gba ẹni nã wọlé nígbàtí ìkún omi dé tí afẹ́fẹ́ sì fẹ́ tí ó bìlù wọ́n. Nítorínã, ẹ kọjá lọ sí ọ́dọ̀ àwọn ènìyàn yí, kí ẹ sì kéde àwọn ọ̀rọ̀ tí èmi ti sọ, títí dé gbogbo ìkangun ayé. 12 Jésù pe àwọn Méjìlá ó sì fi àṣẹ fún wọn—Ó fi ìdáni-lẹ́kọ fún àwọn ará Nífáì èyítí ó jọ Ìwãsù lórí Òkè—Ó sọ ọ̀rọ̀ Ìbùkún nnì—Ìkọ́ni rẹ̀ tayọ òfin Mósè ó sì tún ṣíwájú rẹ̀—A pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn láti wà ní pípé àní gẹ́gẹ́bí òun àti Bàbá rẹ̀ ti wà ní pípé—A fi orí ìwé yĩ wé Máttéù 5. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí parí fún Nífáì, àti fún àwọn tí a ti pè, (báyĩ iye àwọn tí a ti pè, tí nwọ́n sì ti gba agbára àti àṣẹ láti ṣe ìrìbọmi, jẹ́ méjìlá) sì kíyèsĩ, ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, ó sì gbé ohùn rẹ̀ sókè sí wọn, wípé:Alábùkún-fún ni ẹ̀yin bí ẹ̀yin ó bá ṣe àkíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn méjìlá tí èmi ti yàn lãrín yín láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún yín, àti láti jẹ́ ìránṣẹ̃ yín; àwọn ni èmi sì fi agbára fún láti lè ṣe ìrìbọmi fun yín pẹ̀lú omi; lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ìrìbọmi pẹ̀lú omi, ẹ kíyèsĩ, èmi yíò ṣe ìrìbọmi fun yín pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́; nítorínã alábùkún-fún ni ẹ̀yin bí ẹ̀yin ó bá gbà mí gbọ́ tí a sì rì yín bọmi, lẹ́hìn tí ẹ̀yin ti rí mi tí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni. Àti pẹ̀lú, alábùkún-fún jùlọ ni àwọn tí yíò gba àwọn ọ̀rọ̀ yín gbọ́ nítorítí ẹ̀yin ó jẹ́rĩ pé ẹ̀yin ti rí mi, àti pé ẹ̀yin mọ̀ pé èmi ni. Bẹ̃ni, alábùkún-fún ni àwọn tí yíò gba àwọn ọ̀rọ̀ yín gbọ́, tí wọn ó sì rẹ ara wọn sílẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrẹ̀lẹ̀, tí a ó sì rì wọn bọmi, nítorítí a ó bẹ̀ wọ́n wò pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn yíò sì gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Bẹ̃ni, alábùkún-fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí tí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Àti pẹ̀lú, alábùkún-fún ni gbogbo àwọn ẹnití nkẹ́dùn ọkàn, nítorítí a ó tù wọ́n nínú. Alábùkún-fún sì ni àwọn ọlọ́kàn tútù, nítorí àwọn ni yíò jogún ayé. Alábùkún-fún sì ni gbogbo àwọn tí ebi npa àti àwọn tí òungbẹ ngbẹ sí ipa òdodo, nítorí a ó yó wọn pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́. Alábùkún-fún sì ni àwọn alãnú-ènìyàn, nítorí wọn yíò rí ãnú gbà. Alábùkún-fún sì ni gbogbo àwọn onínú funfun, nítorí wọn yíò rí Ọlọ́run. Alábùkún-fún sì ni gbogbo àwọn onílàjà, nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n. Alábùkún-fún sì ni gbogbo àwọn tí a ṣe inúnibíni sí nítorí orúkọ mi, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Alábùkún-fún sì ni ẹ̀yin, nígbati àwọn ènìyàn bá nkẹgan yin, ti wọn si nṣe ínuníbíní si yín, tí wọn sì nfi èké sọ onirũru ohun búburú si yin, nitori mi; Nítorítí ẹ̀yin ó láyọ̀ púpọ̀ ẹ̀yin ó sì ní inú dídùn tí ó pọ̀, nítorí èrè nyín yíò pọ̀ ní ọ̀run; nítorí bẹ̃ni wọ́n ṣe inúnibíni àwọn wòlĩ tí ó ti nbẹ ṣãjú yín. Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, mo fií fún yín kí ẹ̀yin ó jẹ́ iyọ̀ ayé; ṣùgbọ́n bí iyọ̀ nã bá sọ adùn rẹ̀ nù báwo ni ayé yíò ṣe ní iyọ̀? Iyọ̀ nã láti ìgbà nã lọ kò sì ní dára fún ohunkóhun, bíkòṣe kí a sọọ́ sóde kí a sì tẹ̃ mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ ènìyàn. Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, mo fi fún yín kí ẹ̀yin ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn yĩ. Ìlú tí a tẹ̀dó lórí òkè kò lè farasin. Ẹ kíyèsĩ, njẹ́ ènìyàn ha lè tan iná fìtílà kí ó sì gbée sábẹ́ agbọ̀n bí? Rárá, ṣùgbọ́n yíò gbée lé orí ọ̀pa fìtílà, tí yíò sì fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹnití nbẹ nínú ilé; Nítorínã ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín ó mọ́lẹ̀ tóbẹ̃ níwájú àwọn ènìyàn yĩ, kí wọn ó lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn ó sì máa yin Bàbá yín tí nbẹ lọ́run lógo. Ẹ máṣe rò wípé èmi wá láti pa òfin tàbí àwọn wòlĩ run. Èmi kò wá láti parun, bíkòṣe láti múṣẹ; Nítorí lóotọ́ ni mo wí fún yín, ohun kíkiní kan nínú òfinko tĩ kọjá, bí ó ti wù kí ó kéré tó, sugbọn nínú mi a ti múu ṣẹ. Ẹ sì kíyèsĩ, èmi ti fún yín ní òfin àti àwọn àṣẹ Bàbá mi, kí ẹ̀yin ó lè gbàgbọ́ nínú mi, kí ẹ̀yin ó sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́. Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ní àwọn àṣẹ nã níwájú yín, a sì ti mú òfin nã ṣẹ. Nítorínã ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi kí a sì gbà yín là; nítorí lóotọ́ ni mo wí fún yín, pé bíkòṣepé ẹ̀yin pa àwọn àṣẹ mi mọ́, èyítí èmi ti pa láṣẹ fún yín ni àkokò yí, ẹ̀yin kò lè wọ ìjọba ọ̀run bí ó ti wù kí ó rí. Ẹ̀yin ti gbọ́ pé a ti sọọ́ láti ẹnu àwọn ará ìgbà nnì, a sì tún kọ́ọ fún yín, pé ìwọ kò gbọ́dọ̀ pànìyàn, ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì pànìyàn yíò wà nínú ewu ìdájọ́ Ọlọ́run; Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá bá arákùnrin rẹ̀ bínú yíò wà nínú ewu ìdájọ́ Ọlọ́run. Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì wí fún arákùnrin rẹ̀, pé: Rákà, yíò wà nínú ewu ọwọ́ àwọn àjọ ìgbìmọ̀; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì wípé, Ìwọ aṣiwèrè, yíò wà nínú ewu iná ọ̀run àpãdì. Nítorínã, bí ẹ̀yin yíò bá wá sí ọ̀dọ̀ mi, tàbí bí ẹ bá ní ìfẹ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ mi, tí ẹ sì rántí pé arákùnrin yín ní ohun kan nínú sí yín— Ẹ sì tọ arákùnrin yin lọ kí ẹ sì kọ́ bá arákùnrin yín làjà ná, nígbànã ni kí ẹ tó wá sí ọ́dọ̀ mi tọkàn-tọkàn, èmi yíò sì gbà yín, Bá ọ̀tá rẹ rẹ́ kankan nígbàtí ìwọ wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ̀, kí o má bã rí ọ mú kí a sì gbé ọ sọ sínú túbú. Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kì yíò jáde kúrò níbẹ̀ títí ẹ̀yin ó fi san gbogbo owó rẹ̀ láìku ẹyọ sẹ́nínì kan. Nígbàtí ẹ̀yin bá sì wà nínú túbú njẹ́ ẹ̀yin ha lè san ẹyọ sẹ́nínì bí? Lóotọ́, lóotọ́, mo wí fún yín, Rárá. Ẹ kíyèsĩ, a ti kọọ́ láti ọwọ́ àwọn ará ìgbà nnì, pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà; Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan, láti ṣe ìfẹ́-kúfẹ síi, ó ti bã ṣe panṣágà tán ní ọkàn rẹ̀. Ẹ kíyèsĩ, èmi fún yín ní òfin kan, pé kí ẹ̀yin ó máṣe jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn ohun wọ̀nyí ó wọ inú ọkàn yín lọ; Nítorítí ó sàn kí ẹ̀yin ó sẹ́ ara yín pẹ̀lú àwọn ohun wọ̀nyí nínú èyítí ẹ̀yin ó gbé àgbélèbú yín, dípò èyítí a ó fi sọ yín sínú ọ̀run àpãdì. A ti kọọ́, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí ó fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lée lọ́wọ́. Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ bíkòṣe nítorí àgbèrè, ó múu ṣe panṣágà; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ẹnití a kọ̀ sílẹ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà. Àti pẹ̀lú, a ti kọọ́, ìwọ kò gbọ́dọ̀ búra, bíkòṣe kí ìwọ ó sì mú ìbúra rẹ ṣẹ fún Olúwa; Ṣùgbọ́n lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, ẹ máṣe búra rárá; ìbã ṣe ìfi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni íṣe; Tàbí ayé, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ni íṣe; Bẹ̃ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun kan di dúdú tàbí funfun; Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín jẹ́ Bẹ̃ni, bẹ̃ni; Bẹ̃kọ́, bẹ̃kọ́; nítorípéohunkóhun tí a bá sọ tí ó bá ju ìwọ̀nyí lọ jẹ́ ti ibi. Sì kíyèsĩ, a ti kọọ́, ojú kan fún ojú kan, àti ehín kan fún ehín kan; Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, pé kí ẹ máṣe fi ibi san ibi, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbá ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ti èkejì síi pẹ̀lú; Bí ẹnikẹ́ni bá sì fi ọ́ sùn ní ilé ẹjọ́ tí ó sì gbà ọ́ ní ẹ̀wù lọ, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú; Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi agbára mú ọ rin ìbùsọ̀ kan, bã dé méjì. Fifún ẹnití ó bẽrè lọ́wọ́ rẹ, àti ẹnití ó nfẹ́ láti tọrọ lọ́wọ́ rẹ kí ìwọ ó máṣe yí ojú rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Kí ẹ sì kíyèsĩ a ti kọọ́ pẹ̀lú, pé ìwọ gbọ́dọ̀ fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ kí o sì kórìra ọ̀tá rẹ; Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ mo wí fún yín, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín, ẹ súre fún àwọn ẹnití nfi yín ré, ẹ máa ṣe ọ́re fún àwọn tí ó kórìra yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tí nfi àránkan bá yín lò tí wọn nṣe inúnibíni sí yín; Kí ẹ̀yin ó lè jẹ́ ọmọ Bàbá yín tí nbẹ ní ọ̀run; nítorítí ó mú òòrùn rẹ̀ ràn sí órí ẹni búburú àti ẹni rere. Nítorínã àwọn ohun ti ìgbà nnì, tí íṣe èyítí ó wà lábẹ́ òfin, nínú mi ni a mú ṣẹ. Ohun ti àtijọ́ ti dópin, ohun gbogbo sì di titun. Nítorínã, mo fẹ́ kí ẹ̀yin ó wà ní pípé àní gẹ́gẹ́bí èmi, tàbí Bàbá yín tí nbẹ ní ọ̀run ti wà ní pípé. 13 Jésù kọ́ àwọn ará Nífáì ní Àdúrà Olúwa—Pé kí wọn ó to ìṣúra jọ ní ọ̀run—A pàṣẹ fún Àwọn Méjìlá nnì nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn láti máṣe àníyàn nítorí ohun ti ara—A fi orí ìwé yĩ wé Máttéù 6. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Lóotọ́, lóotọ́, mo wípé èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó máa ṣe ìtọrẹ-ãnú fún àwọn òtòṣì; ṣùgbọ́n ẹ ṣe àkíyèsí láti má ṣe ìtọrẹ-ãnú níwájú ènìyàn kí wọn ó lè rí yín; bíkòṣe bẹ̃ ẹ̀yin kò ní èrè lọ́dọ̀ Bàbá yín tí nbẹ ní ọ̀run. Nítorínã, nígbàtí ẹ̀yin yíò bá ṣe ìtọrẹ-ãnú yín, ẹ máṣe fun fèrè níwájú yín, bí àwọn àgàbàgebè ti íṣe ní sínágọ́gù àti ní òpópó ọ̀nà, kí wọn ó lè gba ìyìn ènìyàn. Lóotọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ná. Ṣùgbọ́n nígbàtí ẹ̀yin bá nṣe ìtọrẹ-ãnú, ẹ máṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì yín kí ó mọ́ ohun tí ọwọ́ ọ̀tun yín nṣe; Kí ìtọrẹ-ãnú yín ó lè wà ní ìkọ̀kọ̀; tí Bàbá yín tí ó ri ní ìkọ̀kọ̀, òun tìkararẹ̀ yíò san án fún yín ní gbangba. Nígbàtí ẹ̀yin bá sì ngbàdúrà, ẹ máṣe dàbí àwọn àgàbàgebè, nítorí wọ́n fẹ́ láti máa dúró gbàdúrà nínú sínágọ́gù, àti ní ìkángun òpópó ọ̀nà, kí ènìyàn bã lè rí wọn. Lóotọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ná. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, nígbàtí ẹ̀yin bá ngbàdúrà, ẹ wọ inú ìyẹ̀wù yín lọ, nígbàtí ẹ̀yin bá sì ti sé ilẹ̀kùn yín, ẹ gbàdúrà sí Bàbá yín tí nbẹ ní ìkọ̀kọ̀; Bàbá yín, ẹnití ó ri ní ìkọkọ̀, yíò san án fún yín ní gbangba. Ṣùgbọ́n nígbàtí ẹ̀yin bá ngbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán, bíàwọn kèfèrí, nítorítí wọ́n ṣèbí a ó ti ìtorí ọ̀rọ̀ púpọ̀ wọn gbọ́ tiwọn. Nítorínã, kí ẹ̀yin ó máṣe dàbí wọn, nítorítí Bàbá yín mọ́ ohun tí ẹ̀yin ṣe aláìní kí ẹ̀yin ó tó bẽrè lọ́wọ́ rẹ̀. Nítorínã báyĩ ni kí ẹ̀yin ó máa gbàdúrà: Bàbá wa tí nbẹ ní ọ̀run, ọ̀wọ̀ ni fún orúkọ rẹ. Ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe ní ayé bí a ti íṣe ní ọ̀run. Dárí igbèsè wa jì wá, bí àwa ti ndáríjì àwọn onígbèsè wa. Ma sì fà wá sínú ìdánwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ bìlísì. Nítorí tìrẹ ni ìjọba, àti agbára, àti ògo títí láé. Àmín. Nítorí, bí ẹ̀yin bá dárí ìrékọjá àwọn ènìyàn jì wọ́n, Bàbá yín ti ọ̀run nã yíò dáríjì yín; Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá dárí ìrékọjá àwọn ènìyàn jì wọ́n, bákannã ni Bàbá yín kò ní dári ìrékọjá yín jì yín. Àti pẹ̀lú, nígbàtí ẹ̀yin bá ngbãwẹ̀, ẹ máṣe dàbí àwọn àgàbàgebè tí nfajúro, nítorítí wọn a bá ojú jẹ́, kí wọn ó lè fihàn fún àwọn ènìyàn pé wọn ngbãwẹ̀. Lóotọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ná. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, nígbàtí ẹ̀yin bá ngbãwẹ̀, ẹ fi òróró kun orí yín, kí ẹ sì bọ́jú yín; Kí ẹ̀yin kí ó máṣe fi ara hàn fún ènìyàn pé ẹ ngbãwẹ̀, bíkòṣe fún Bàbá yín, ẹnití nbẹ ní ìkọ̀kọ̀; Bàbá yín tí í sì ri ní ìkọ̀kọ̀, yíò sì san án fún yín ní gbangba. Ẹ máṣe to ìṣura jọ fún ara yín ní ayé, níbití kòkòrò àti ìpãrà yíò bã jẹ́, àti tí àwọn olè yíò wọlé wá tí wọn ó sì jalè; Ṣùgbọ́n ẹ to ìṣura yín jọ fún ara yín ní ọ̀run, níbití kòkòrò àti ìpãrà kò lè bã jẹ́, àti níbití àwọn olè kò lè wọlé wá kí wọn ó sì jalè. Nítorí níbití ìṣúra yín bá gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yíò wà pẹ̀lú. Ojú ni fìtílà ara; nítorínã, bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀, gbogbo ara rẹ ni yíò kún fún ìmọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá ṣókùnkùn, gbogbo ara rẹ ni yíò kún fún òkùnkùn. Nítorínã, bí ìmọ́lẹ̀ ti nbẹ nínú yín bá jẹ́ òkùnkùn, báwo ni òkùnkùn nã yíò ti tó! Kò sí ẹnití ó lè sìn olúwa méjì; nítorí yálà yíò kórìra ọ̀kan, kí ó sì fẹ́ èkejì, tàbí kí ó faramọ́ ọ̀kan kí ó sì fi èkejì ṣẹ̀sín. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti Mámónì. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó kọ ojú sí àwọn méjìlá nnì tí ó ti yàn, ó sì wí fún wọn pé: Ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí èmi ti sọ. Nítorí ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ni èmi ti yàn láti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn yĩ. Nítorínã ni mo wí fún yín, pé kí ẹ máṣe ṣe àníyàn nítorí ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ̀yin yíò jẹ, tàbí ohun tí ẹ̀yin yíò mu; tàbí fún ara yín, ohun tí ẹ̀yin yíò fi bora. Njẹ́ ẹ̀mí kò ha ju oúnjẹ lọ bí, tàbí ara kò ha ju aṣọ lọ bí? Ẹ kíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn kĩ fúrúgbìn, bẹ̃ni wọn kĩ kórè tàbí kí wọn kójọ sínú abà; síbẹ̀ Bàbá yín ti ọ̀run a máa bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha dára jù wọ́n lọ bí? Tani nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún gíga rẹ̀? Èéṣe tí ẹ̀yin sì fi nṣe àníyàn nítorí ẹ̀wù? Ẹ kíyèsí àwọn lílì tínbẹ ní ọ̀dàn bí wọ́n ti ndàgbà; wọn kĩ ṣiṣẹ́, bẹ̃ni wọn kĩ rànwú; Síbẹ̀ èmi wí fún yín, pé a kò ṣe Sólómọ́nì pãpã, ní ọ̀ṣọ̀ nínú gbogbo ògo rẹ̀, tó bí ọ̀kan nínú àwọn yĩ. Nítorí-eyi, bí Ọlọ́run bá wọ koríko ìgbẹ́ ní aṣọ bẹ̃, èyítí ó wà lóni, tí a sì fií ṣe ohun ìdáná lọ́la, melomelo ni kì yíò fi lè wọ̀ yín láṣọ, bí ẹ̀yin kò bá jẹ onigbagbọ kekere. Nítorínã ẹ máṣe ṣe àníyàn, wípé, Kíni a ó jẹ? Tàbí, Kíni a ó mu? Tàbí, Aṣọ wo ni àwa ó wọ̀? Nítorítí Bàbá yín ti ọ̀run mọ̀ pé ẹ̀yin kò lè ṣe aláìní gbogbo ohun wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ẹ tètè máa wá ìjọba Ọlọ́run ná, àti òdodo rẹ̀, gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí ni a ó sì fi fún yín. Nítorí kí ẹ máṣe ṣe àníyàn fún ọ̀la, nítorítí ọ̀la yíò ṣe àníyàn fún ohun tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ òní sã tó fún un. 14 Jésù pàṣẹ pé: Ẹ máṣe dání ní ẹjọ́; ẹ bẽrè lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹ máa kíyèsára fún àwọn wòlĩ èké—Ó ṣe ìlérí ìgbàlà fún àwọn tí ó bá ṣe ìfẹ́ ti Bàbá—A fi orí ìwé yĩ wé Máttéù 7. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó tún yíjú padà sí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã ó sì tún la ẹnu rẹ̀ sí wọn, wípé: Lóotọ́, lóotọ́, èmi wí fún yín, Ẹ máṣe dání ní ẹjọ́, kí a má bã dá yín ní ẹjọ́. Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni á ó ṣe fún yín; àti pé irú òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ̀n, òun ni á ó sì fi wọ̀n fún yín. Èétiṣe tí ìwọ sì nwo ẽrún igi tí nbẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kò kíyèsí ìtí igi tí nbẹ ní ojú ara rẹ? Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé: Jẹ́ kí èmi ó yọ ẽrún igi tí nbẹ ní ojú rẹ kúrò—sì wọ́, ìtí igi nbẹ ní ojú ìwọ tìkararẹ̀? Ìwọ àgàbàgebè, tètèkọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná; nígbànã ni ìwọ yíò sì ríràn kedere láti yọ ẽrún igi tí nbẹ ní ojú arákùnrin rẹ̀ kúrò. Ẹ máṣe fi ohun tí iṣe mímọ́ fún àwọn ajá, kí ẹ má sì ṣe sọ péálì yín síwájú ẹlẹ́dẹ̀, kí wọn ó má bã fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, tí wọn a sì tún yípadà, wọn a sì bù yín ṣán. Ẹ bẽrè, a ó sì fi fún yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣíi sílẹ̀ fún yín. Nítorípé ẹnikẹ́ni tí ó bá bẽrè, nrí gbà; ẹnití ó bá sì wá kiri nrí; ẹnití ó bá sì kànkùn, ni a ò síi sílẹ̀ fún. Tàbí tani ọkùnrin nã tí mbẹ nínú yín, bí ọmọ rẹ̀ bèrè àkàrà, tí yíò fí òkúta fún un? Tàbí bí ó bèrè ẹja, tí yíò fún un ní ejò? Njẹ́ bí ẹ̀yin tí íṣe ènìyàn búburú, bá mọ̀ bí a ti fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, melomelo ni Bàbá yín tí nbẹ ní ọ̀run yíò fi ohun rere fún àwọn tí ó bá bẽrè lọ́wọ́ rẹ̀? Nítorínã, gbogbo ohunkóhun tí ẹ̀yin bá nfẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ̃ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́, nítorí-èyí ni òfin àti àwọn wòlĩ. Ẹ bá ẹnu-ọ̀nà híhá wọlé; nítorí gbọ́rò ni ẹnu-ọ̀nà nã, fífẹ̀ sì ni ojú-ọ̀nà nã, èyítí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ẹnití nbá ibẹ̀ wọlé; Nítorípé híhá ni ẹnu-ọ̀nà nã, tọ́ró sì ni ojú-ọ̀nà nã, èyítí ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn ẹnití nríi. Ẹ máa kíyèsára nítorí àwọn wòlĩ èkè, tí wọn ntọ̀ yín wá nínú awọ àgùtàn, ṣùgbọ́n apanijẹ ìkòkò ni wọ́n nínú. Ẹ̀yin yíò mọ̀ wọ́n nípa èso wọn. Njẹ́ ènìyàn a máa ká èso àjàrà lórí ẹ̀gún ọ̀gàn, tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀wọ̀n bí? Gẹ́gẹ́ bẹ̃ gbogbo igi rere ni íso èso rere; ṣùgbọ́n igi búburú ni íso èso búburú. Igi rere kò lè so èso búburú, bẹ̃ni igi búburú kò sì lè so èso rere. Gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a ó ké lulẹ̀, a ó sì wọ̣́ sínú iná. Nítorí-èyí, nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọ́n. Kì íṣe gbogbo ẹnití npè mi ní Olúwa, Olúwa, ni yíò wọlé sínú ìjọba ọ̀run; bíkòṣe ẹnití nṣe ìfẹ́ ti Bàbá mi tí nbẹ ní ọ̀run. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yíò wí fún mi ní ọjọ́ nã pé: Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ bí, àti ní orúkọ rẹ ni àwa fi lé àwọn èṣù jáde, àti ní orúkọ rẹ ni a fi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu nlá? Nígbànã ni èmi ó sì jẹ́wọ́ fún wọn pé: Èmi kò mọ̀ yín rí; ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Nítorínã, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí èmi sọ wọ̀nyí tí ó sì nṣe wọ́n, èmi ó fi wé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, tí ó kọ́ ilé rẹ sí orí àpáta— Òjò sì rọ̀, ìkun omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, ó sì bìlu ilé nã; kò sì wó, nítorí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí tí kò sì ṣe wọ́n, òun ni èmi ó fi wé aṣiwèrè ènìyàn kan, tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn— Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bìlu ilé nã; ó sì wó, ìwọ rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ. 15 Jésù wípé a mú òfin Mósè ṣẹ nínú òun—Àwọn ará Nífáì ni àwọn àgùtàn míràn nã nípa èyítí ó sọ ní Jerúsálẹ́mù—Nítorí àìṣedẽdé wọn, àwọn ènìyàn Olúwa tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù kò mọ̀ nípa àwọn àgùtàn Ísráẹ́lì tí a ti fọ́nká. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti parí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀nyí ó wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã yíká, ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti gbọ́ àwọn ohun wọ̀nyí tí èmi ti kọ́ kí èmi ó tó gòkè lọ sí ọ́dọ̀ Bàbá mi; nítorínã, ẹnìkẹ́ni tí ó bá rántí àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí tí ó sì nṣe wọ́n, òun ni ẹnití èmi yíò gbé dìde ní ọjọ́ ìkẹhìn. Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó wòye pé àwọn kan wà lãrín wọn tí ẹnu nyà wọ́n, tí wọ́n sì nṣe hà nípa ohun tí ó fẹ́ kí àwọn ó ṣe nípa òfin Mósè; nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sọ wípé àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ, àti pé ohun gbogbo ti di titun kò yé wọn. Ó sì wí fún wọn pé: Ẹ máṣe jẹ́ kí ó yà yín lẹ́nu pé mo wí fúnyín pé àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ, àti pé ohun gbogbo ti di titun. Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín pé; òfin tí a fi fún Mósè ti di ìmúṣẹ. Ẹ kíyèsĩ, èmi ni ẹnití ó fi òfin nã fún wọn, èmi sì ni ẹnití ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi Ísráẹ́lì; nítorínã, òfin nã nínú mi ó ti di mímúṣẹ, nítorítí mo wá láti mú òfin nã ṣẹ; nítorínã ni ó ní òpin. Ẹ kíyèsĩ, èmi kò ṣá àwọn wòlĩ tì, nítorí gbogbo àwọn ohun tí a kò ì múṣẹ nínú mi, lóotọ́ ni mo wí fún yín, wọn yíò di mímúṣẹ pátápátá. Àti nítorípé èmi ti wí fún yín pé ohun àtijọ́ ti kọjá lọ, èmi kò ṣá àwọn ohun tí a ti sọ nípa àwọn ohun tí nbọ̀ tì. Nítorí ẹ kíyèsĩ, májẹ̀mú èyítí èmi ti bá àwọn ènìyàn mi dá kò ì di mímúṣẹ tán; ṣùgbọ́n òfin èyítí a fún Mósè ní òpin nípasẹ̀ mi. Ẹ kíyèsĩ, èmi ni òfin, àti ìmọ́lẹ̀ nã. Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé mi, kí ẹ sì forítì í dé òpin, ẹ̀yin yíò sì yè; nítorí ẹnití ó bá forítĩ dé òpin ni èmi yíò fún ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ kíyèsĩ, èmi ti fún yín ní àwọn òfin; nítorínã ni kí ẹ pa àwọn òfin mi mọ́. Èyí sì ni òfin àti àwọn wòlĩ, nítorítí nwọ́n jẹ́risí mi nítòọ́tọ́. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọn yĩ tán, ó wí fún àwọn méjìlá nnì àwọn ẹnití ó ti yàn: Ẹ̀yin ni ọmọ-ẹ̀hìn mi; ẹ̀yin sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn yĩ, àwọn tí íṣe ìyókù ti ilé Jósẹ́fù. Ẹ sì kíyèsĩ, ilẹ̀ ìní yín ni èyí; Bàbá sì ti fi fún yín. Bàbá kò sì fi ìgbà kan fún mi ní àṣẹ pé kí èmi ó sọọ́ fún àwọn arákùnrin yín tí nbẹ ní Jerúsálẹ́mù. Bẹ̃ni kò sì sí ìgbà tí Bàbá fún mi ní àṣẹ pé kí èmi ó sọ fún wọn nípa àwọn ẹ̀yà ìdílé Ísráẹ́lì, àwọn tí Bàbá ti darí wọn jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã. Èyí ni Bàbá pàṣẹ fún mi, pé kí èmi ó sọ fún wọn: Pé èmi ní àwọn àgùtàn míràn tí wọn kì íṣe ti agbo yĩ; àwọn pẹ̀lú ni èmi níláti mú wá, wọn yíò sì gbọ́ ohùn mi; agbo kanṣoṣo ni yíò sì wà, àti olùṣọ́-àgùtàn kanṣoṣo. Àti nísisìyí, nítorí ọrùnlíle àti àìgbàgbọ́, ọ̀rọ̀ mi kò yé wọn; nítorínã ni Bàbá pàṣẹ fún mi láti ma sọ nípa ohun yĩ mọ́ fún wọn. Ṣùgbọ́n, lóotọ́, èmi wí fún yín pé Bàbá ti pàṣẹ fún mi, èmi sì sọọ́ fún yín, pé a pín yín níyà kúrò lãrín wọn nítorí àìṣedẽdé wọn; nítorínã ni ó ṣe jẹ́ nítorí àìṣedẽdé wọn ni wọn kò mọ̀ nípa yín. Àti lóotọ́, mo tún wí fún yín pé àwọn ẹ̀yà míràn ni Bàbá ti pínníyà kúrò lãrín wọn; àti pé nítorí àìṣedẽdé wọn ni wọn kò fi mọ̀ nípa wọn. Àti lóotọ́ ni mo wí fún yín, pé ẹ̀yin ni àwọn ẹnití èmi sọ nípa wọn pé: Èmi ní àwọn àgùtàn míràn tí wọn kì íṣe ti agbo yĩ; àwọn pẹ̀lú ni èmi ní láti mú wá, wọn yíò sì gbọ́ ohùn mi; agbo kanṣoṣo ni yíò sì wà, àti olùṣọ́-àgùtàn kanṣoṣo. Ọ̀rọ̀ mi kò sì yé wọn, nítorítí wọ́n rò wípé àwọn Kèfèrí ni; nítorítí kò yé wọn pé àwọn Kèfèrí yíò yí lọ́kàn padà nípasẹ̀ ìwãsù wọn. Ọ̀rọ̀ mi kò sì yé wọn nígbàtí èmi wípé wọn yíò gbọ́ ohùn mi; ọ̀rọ̀ mi kò sì yé wọn pé àwọn Kèfèrí kò lè gbọ́ ohùn mi ni gba kankan—pé èmi kò lè fi ara mi hàn sí wọn bíkòṣe nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti gbọ́ ohun mi pẹ̀lú, ẹ sì ti rí mi; àgùtàn mi ni ẹ̀yin sì íṣe, a sì ti kà yín mọ́ ara àwọn tí Bàbá ti fifún mi. 16 Jésù yíò bẹ̀ àwọn míràn nínú àwọn àgùtàn Ísráẹ́lì tí ó sọnù wò—Ní àwọn ọjọ́ ti ìkẹhìn ìhìn-rere nã yíò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí lẹ́hìnnã yíò lọ sí ìdílé Ísráẹ́lì—Àwọn ènìyàn Olúwa yíò ríi ní ojúkojú nígbàtí yíò mú Síónì padà bọ̀ wá. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín pé èmi ní àwọn àgùtàn míràn, tí wọn kò sí nínú ilẹ̀ yĩ, bẹ̃ni wọn kò sí nínú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, bẹ̃ni wọn kò sí nínú ilẹ̀ nnì tí ó wà ní àyíká ibití èmi ti lọ jíṣẹ́ ìránṣẹ́. Nítorí àwọn tí èmi nsọ̀rọ̀ nípa wọn ni àwọn tí wọn kò ì gbọ́ ohùn mi; bẹ̃ni èmi kò ì fi ìgbà kan fi ara hàn sí wọn. Ṣùgbọ́n èmi ti gba òfin kan láti ọ̀dọ̀ Bàbá mi pé kí èmi ó lọ sí ọ̀dọ̀ wọn, àti pé wọn yíò gbọ́ ohùn mi, a ó sì kà wọ́n mọ́ àwọn àgùtàn mi, láti lè jẹ́ kí agbo kanṣoṣo ó wà àti olùṣọ́-àgùtàn kanṣoṣo; nítorínã ni èmi yíò lọ láti fi ara mi hàn sí wọn. Èmi sì pàṣẹ fún yín pé kí ẹ̀yin ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí lẹ́hìn tí èmi bá ti lọ, pé bí àwọn ènìyàn mi tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn tí ó ti rí mi tí wọ́n sì ti wà pẹ̀lú mi nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, bí wọn kò bá bẽrè lọ́wọ́ Bàbá ní orúkọ mi, kí wọn ó ní ìmọ̀ nípa yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, àti nípa àwọn ẹ̀yà míràn nnì tí wọn kò mọ̀ nípa wọn, pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí ẹ̀yin yíò kọ yíò wà ní ìpamọ́ a ó sì fi wọ́n hàn fún àwọn Kèfèrí, pé nípasẹ̀ ẹ̀kún àwọn Kèfèrí, ìyókù irú-ọmọ wọn, àwọn tí a ó fọ́nká kiri orí ilẹ̀ ayé nítorí àìgbàgbọ́ wọn, ki wọ́n lè wọle a ó mú wọn sínú ìmọ̀ nípa mi, Olùrapadà wọn. Nígbànã ni èmi yíò sì kó wọn jọ láti igun mẹ́rẹ̃rin ayé; nígbànã ni èmi yíò sì mú májẹ̀mú nã èyítí Bàbá ti dá pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ìdílé Ísráẹ́lì ṣẹ. Alabukun sì ni fún àwọn Kèfèrí, nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú mi, nínú àti nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, èyítí o jẹ̃rí sí wọn nípa mi àti nípa Bàbá. Ẹ kíyèsĩ, nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú mi, bẹ̃ni Bàbá wí, àti nítorí àìgbàgbọ́ rẹ, A! ìdílé Ísráẹ́lì, ní ọjọ́ ìkẹhìn ni òtítọ́ yíò tọ àwọn Kèfèrí wá, kí ẹ̀kún àwọn ohun wọ̀nyí ó lè di mímọ̀ sí wọn. Ṣùgbọ́n ègbé ni, bẹ̃ni Bàbá wí, fún àìgbàgbọ́ àwọn Kèfèrí—nítorípé l’áìṣírò wọ́n ti jáde wá sí orí ilẹ̀ yĩ, tí wọ́n sì fọ́n àwọn ènìyàn mi tí wọn jẹ́ ti ìdílé Ísráẹ́lì ká; àwọn ènìyàn mi tí wọ́n jẹ ti ìdílé Ísráẹ́lì ni wọ́n ti lé jáde kúrò lãrín wọn. tí wọ́n sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ wọn; Àti nítorí ãnú Bàbá sí àwọn Kèfèrí, àti ìdájọ́ Bàbá pẹ̀lú, lórí àwọn ènìyàn mi tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé Ísráẹ́lì, lóotọ́, lóotọ́ ni mo wí fún yín, pé lẹ́hìn gbogbo èyí, tíèmi sì ti mú kí wọn ó kọlù àwọn ènìyàn mi tí wọn jẹ́ ti ìdílé Ísráẹ́lì, àti kí wọn ó pọ́n wọn lójú, àti kí wọn ó pa wọ́n, àti kí wọn ó lé wọn jáde kúrò lãrín wọn, àti kí wọn ó kórìra wọn, àti kí wọn ó di òṣé àti ìfiṣẹ̀sìn lãrín wọn— Báyĩ sì ni Bàbá pàṣẹ pé kí èmi ó wí fún yín: Ní ọjọ́ nã nígbàtí àwọn Kèfèrí yíò ṣẹ̀ sí ìhirere mi, àti tí wọn yíò kọ ẹ̀kún ìhìn-rere mi, tí wọn yíò sì rú ọkàn wọn sókè nínú ìgbéraga ọkàn wọ́n lórí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti lórí gbogbo ènìyàn tí ó wà nínú gbogbo ayé, àti nígbàtí wọn yíò kún fún onírurú irọ́ pípa, àti ẹ̀tàn, àti ìwà ìkà, àti onírurú ìwà àgàbàgebè, àti ìpànìyàn, àti iṣẹ́ àlùfã àrekérekè, àti ìwà àgbèrè, àti ti ohun ìríra ìkọ̀kọ̀; àti ti wọ́n bá sì ṣe gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí àti pé bí wọ́n bá sì kọ ẹ̀kún ìhìnrere mi nã, ẹ kíyèsĩ, ni Bàbá wí, èmi yíò mú ẹ̀kún ìhìn-rere mi kúrò lãrín wọn. Àti nígbànã ni èmi yíò rántí májẹ̀mú mi èyítí èmi ti bá àwọn ènìyàn mi dá, A! ìdílé Ísráẹ́lì, èmi yíò sì mú ìhìn-rere mi tọ̀ wọ́n wá. Èmi yíò sì fi hàn ọ́, A! ìdílé Ísráẹ́lì, pé àwọn Kèfèrí kì yíò ní agbára lórí rẹ; ṣùgbọ́n èmi yíò rántí májẹ̀mú mi sí ọ, A! ìdílé Ísráẹ́lì, ìwọ yíò sì wá sínú ìmọ̀ ẹkun ìhìn-rere mi. Ṣùgbọ́n bí àwọn Kèfèrí yíò bá ronúpìwàdà tí wọn sì padà sí ọ̀dọ̀ mi, ni Bàbá wí, ẹ kíyèsĩ a ó kà wọ́n mọ́ àwọn ènìyàn mi A! ìdílé Ísráẹ́lì. Èmi kò sì ní gbà kí àwọn ènìyàn mi, tí wọn jẹ́ ti ìdílé Ísráẹ́lì, ó kọjá lãrín wọn, kí wọn ó tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ni Bàbá wí. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá yí padà sí ọ̀dọ̀ mi, kí wọn ó sì fetísílẹ̀ sí ohùn mi, èmi yíò jẹ́ kí wọn, bẹ̃ni, èmi yíò jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi, A! ìdílé Ísráẹ́lì, kí wọn ó kọjá lọ lãrín wọn, kí wọn ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn ó sì dà bí iyọ̀ tí ó ti sọ adùn rẹ̀ nù, tí kò sì dára mọ́ fún ohunkóhun ṣùgbọ́n kí a dã sóde, àti kí a tẹ̃ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mi, A! ìdílé Ísráẹ́lì. Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, báyĩ ni Bàbá ti pãláṣẹ fún mi—pé kí èmi ó fún àwọn ènìyàn yí ní ilẹ̀ yĩ fún ìní wọn. Nígbànã ni ọ̀rọ̀ wòlĩ Isaiah yíò di mìmúṣẹ, èyítí ó wípé: Àwọn àlóre rẹ yíò gbé ohùn sókè; wọn yíò jùmọ̀ kọrin pẹ̀lú ohùn nã, nítorítí wọn yíò ríi ní ojúkojú nígbàtí Olúwa yíò mú Síónì padà. Ẹ bú sí ayọ̀, ẹ jùmọ̀ kọrin, ẹ̀yin ibi ahoro Jerúsálẹ́mù; nítorítí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó ti ra Jerúsálẹ́mù padà. Olúwa ti fi apá rẹ̀ mímọ́ hàn ní ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; gbogbo ìkangun ayé ni yíò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run. 17 Jésù sọ fún àwọn ènìyàn nã kí wọn ó ronú nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí wọn ó sì gbàdúrà fún òye nípa wọn—Ó wo àwọn aláìsàn wọn sàn—Ó gbàdúrà fún àwọn ènìyàn nã, ó sì lo èdè tí ẹnikẹ́ni kò lè kọ sílẹ̀—Àwọn ángẹ́lì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ọmọwẹ́wẹ́ wọn, iná sì yí wọn ká. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Ẹ kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó tún wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã yíká, ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ àsìkò mi ti dé tan. Mo wòye pé ẹ wà láìlágbára, pé ẹ kò lè ní òye nípa gbogbo ọ̀rọ̀ mi èyítí Bàbá pàṣẹ fún mi láti wí fún yín ní àkokò yìi. Nítorínã, ẹ lọ sínú ilé yín, kí ẹ sì ronú lé àwọn ohun tí èmi ti sọ, kí ẹ sì bẽrè lọ́wọ́ Bàbá, ní orúkọ mi, kí ó lè yé yín, kí ẹ sì palẹ̀ ọkàn yín mọ́ fún ọ̀la, èmi yíò sì tún tọ̀ yín wá. Ṣùgbọ́n nísisìyí èmi ó tọ Bàbá lọ, àti láti fi ara mi hàn fún àwọn ẹ̀yà Ísráẹ́lì tí ó sọnù, nítorítí wọn kò sọnù sí Bàbá, nítorítí ó mọ́ ibití òun ti mú wọn lọ. Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ̀rọ̀ báyĩ tán, ó wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã yíká, ó sì ríi pé wọn nsọkún, wọ́n sì wọ́ ní ìtẹjúmọ́ bí ẹnipé kí wọn ó rọ̣́ láti dúró tì wọn fún ìgbà díẹ̀ si. Ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ, inú mi kún fún ìyọ́nú sí yín. Njẹ́ ẹ̀yin ní aláìsàn lãrín yín? Ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi. Njẹ́ ẹ̀yin ní àwọn amúkun, tàbí afọ́jú, tàbí arọ, tàbí akéwọ́, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí àwọn gbígbẹ, tàbí adití, tàbí tí a pọ́n lójú ní onírurú ọ̀nà? Ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi èmi yíò sì wò wọ́n sàn, nítorítí èmi ní ìyọ́nú sí yín; inú mi kún fún ãnú. Nítorítí mo woye pé ẹyin nfẹ́ kí èmi ó fi hàn yín ohun tí èmi ti ṣe fún àwọn arákùnrin yín ní Jerúsálẹ́mù, nítorítí mo ríi pé ìgbàgbọ́ yín tó kí èmi lè wò yín sàn. Ó sì ṣe nígbàtí ó ti sọrọ báyĩ tán, gbogbo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, jùmọ̀ jáde lọ pẹ̀lú àwọn aláìsàn wọn àti àwọn tí a pọ́n lójú, àti àwọn amúkun wọn, àti pẹ̀lú àwọn afọ́jú wọn àti pẹ̀lú àwọn odi wọn, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn tí a pọn lójú ní onírurú ọ̀nà; ó sì wò olúkúlùkù wọ́n sàn, bí wọn ṣe nmú wọn wá sí ọdọ rẹ̀. Gbogbo wọn, àti àwọn tí ó ti wò sàn àti àwọn tí ó wà ní pípé, ni ó wólẹ̀ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì bù ọlá fún un; gbogbo àwọn tí ó lè wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ó wá, àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã fi ẹnu ko ẹsẹ̀ rẹ, tóbẹ̃ tí wọn fi omijé ẹkún wọn wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó pàṣẹ pé kí wọn ó gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn wá. Bẹ̃ni wọn gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn wá, wọ́n sì gbé wọn kalẹ̀ yíká, Jésù sì dìde dúró lãrín wọn; àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã sì fi ãyè sílẹ̀ títí wọ́n fi gbé gbogbo àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó sì ṣe nígbàtí wọn ti gbé gbogbo nwọn wá, Jésù sì dìde dúró lãrín wọn, ó pàṣẹ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã pé kí wọn ó kúnlẹ̀ lé orí ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe nígbàtí wọ́n ti kúnlẹ̀ lé orí ilẹ̀, Jésù kérora nínú ara rẹ̀, ó sì wípé: Bàbá, inú mi bàjẹ́ nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn ìdílé Ísráẹ́lì. Nígbàtí ó sì ti sọ awọn ọ̀rọ̀ wọnyi tán, òun tìkararẹ̀ pẹ̀lú kunlẹ lé órí ilẹ̀; ẹ sì kíyèsĩ ó gbàdúrà sí Bàbá, àwọn ohun tí ó sì gbàdúrà fún ni ẹnìkẹ́ni kò lè kọ sílẹ̀, àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã tí ó gbọ́ọ sì jẹ́ ẹ̀rí síi. Báyĩ sì ni ọ̀nà tí wọ́n fi jẹ̃rí síi: Ojú kò ríi rí, bẹ̃ni etí kò gbọ́ọ rí, àwọn ohun nlá àti ohun ìyanu irú èyítí àwa rí àti tí a gbọ́ tí Jésù bá Bàbá sọ; Kò sì sí ahọ́n tí ó lè sọọ́, tàbí kí ẹnìkẹ́ni ó lè kọọ́, tàbí kí ọkàn ẹnìkẹ́ni ó lè ròo nípa àwọn ohun nlá àti ohun ìyanu gẹ́gẹ́bí àwa ti ríi àti tí a sì gbọ́ọ tí Jésù sọ; kò sì sí ẹnìkẹ́nì tí ó lè mọ̀ irú ayọ̀ tí ó kún ọkàn wa ní àkokò tí àwa gbọ́ọ tí ó gbàdúrà sí Bàbá fún wa. Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti parí àdúrà rẹ̀ sí Bàbá, ó dìde; ṣùgbọ́n ayọ̀ àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã pọ̀ tóbẹ̃ tí wọn kò lè dìde dúró. Ó sì ṣe tí Jésù bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì ní kí wọn ó dìde. Wọn sì dìde kúrò ní ilẹ́, ó sì wí fún wọn pé: Alábùkún-fún ni ẹ̀yin nítorí ìgbàgbọ́ yín. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ayọ̀ mi kún. Nígbàtí ó sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó sọkún, àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã sì jẹ̃rí síi, ó sì gbé àwọn ọmọwẹ́wẹ́wọn, ní ọ̀kọ̣́kan, ó sì súre fún wọn, ó sì gbàdúrà sí Bàbá fún wọn. Nígbàtí ó sì ti ṣe èyí tán ó tún sọkún; Ó sì bá àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã sọ̀rọ̀, ó sì wí fún wọn pé: Ẹ wo àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín. Bí wọn sì ti wò láti kíyèsí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ nã, wọn gbé ojú wọn sókè sí ọ̀run, wọ́n sì ríi tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, wọ́n sì rí àwọn ángẹ́lì tí wọn nsọ̀kalẹ̀ jáde láti ọ̀run bí èyítí iná yí wọn ká; wọn sì sọ̀kalẹ̀ wa, wọn sì yí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ nnì ká, iná sì yí wọn ká; àwọn ángẹ́lì nã sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã sì ríi, wọ́n sì gbọ́ọ, wọ́n sì jẹ̃rí síi; wọ́n sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí wọn nítorítí ẹnìkọ̣́kan wọn ni ó rí tí ó sì gbọ́, olúkúlùkù fúnrarẹ̀; wọn sì pọ̀ níye ní ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹ̃dẹ́gbẹ̀ta ẹ̀mí; wọn sì jẹ́ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé wẹ́wẹ́. 18 Jésù fi ìlànà àmì májẹ̀mu lélẹ̀ lãrín àwọn ará Nífáì—Ó pàṣẹ fún wọn láti máa gbàdúrà ní orúkọ òun ní gbogbo ìgbà—Àwọn tí ó jẹ nínú ara rẹ̀ àti tí ó mu nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ní àìpé ni a ó dá lẹ́bi—Ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã ní agbára láti lè fúnni ní Ẹ̀mí Mímọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Ó sì ṣe tí Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pé kí wọn ó mú àkàrà àti wáìnì wá sí ọ̀dọ̀ òun. Nígbàtí wọn sì ti lọ láti mú àkàrà àti wáìnì nã wá, ó pàṣẹ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã pé kí wọn ó joko lé orí ilẹ̀. Nígbàtí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã ti mú àkàrà àti wáinì nã dé, ó mú lára àkàrà nã ó bũ sí wẹ́wẹ́ ó sì súre síi; ó sì fií fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó jẹẹ́. Nígbàtí wọ́n sì ti jẹ́ tí wọ́n sì ti yó, ó pàṣẹ pé kí wọn ó fi fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã. Nígbàtí àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã sì ti jẹ tí wọn yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã pé: Ẹ kíyèsĩ, ẹnìkan wà ní ãrin yín tí èmi yíò yàn, òun ni èmi yíò sì fún ni agbára láti lè bù àkàrà kí ó sì súré sĩ, kí ó sì fií fún àwọn ènìyàn ìjọ mi,fún gbogbo àwọn tí yíò gbàgbọ́ tí a ó sì rìbọmi ní orúkọ mi. Èyí ni ẹ̀yin yíò sì ṣe àkíyèsí láti ṣe, àní gẹ́gẹ́bí èmi ti ṣe, àní gẹ́gẹ́bí èmi ti bù àkàrà tí emí sì súre sĩ, tí èmi sì fií fún yín. Èyí ni ẹ̀yin yíò ṣe ní ìrántí ara mi, èyítí èmi ti fi hàn yín. Yíò sì jẹ́ ẹ̀rí níwájú Bàbá pé ẹ̀yin ṣe ìrántí mi nígbà-gbogbo. Bí ẹ̀yin bá sì ṣe ìrántí mi nígbà-gbogbo, nígbànã ni Ẹ̀mí mi yíò wà pẹ̀lú yín. Ó sì ṣe nígbàtí ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pé kí wọn ó mu nínú wáìnì tí ó wà nínú ago kí wọn ó sì mu lára rẹ̀, àti pé kí wọn ó fi fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã kí wọn ó lè mu nínú rẹ̀. Ó sì ṣe tí wọn ṣe bẹ̃, wọ́n sì mu nínú rẹ̀ wọ́n sì yó, wọn sì fi fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, wọ́n sì mu, wọ́n sì yó. Nígbàtí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã si ti ṣe eleyĩ, Jésù wí fún wọn pé: Alábùkún-fún ni ẹ̀yin íṣe nítorí ohun yĩ èyítí ẹ̀yin ti ṣe, nítorítí èyĩ ni ìmúṣẹ àwọn òfin mi, èyí sì ṣe ìjẹ̃rí sí fún Bàbá pé ẹ̀yin ní ìfẹ́ láti ṣe èyítí mo ti pa láṣẹ fún yín. Èyí sì ni kí ẹ̀yin ó ṣe ní ìgbà gbogbo fún àwọn tí ó ti ronúpìwàdà àti tí a sì rìbọmi ní orúkọ mi; ẹ̀yin ó sì ṣeé ní ìrántí ẹ̀jẹ̀ mi, èyítí èmi ti ta sílẹ̀ fún yín, pé kí ẹ̀yin ó lè ṣe ìjẹ̃rí sí fún Bàbá pé ẹ̀yin nrántí mi ní ìgbà gbogbo. Bí ẹ̀yin bá sì nrántí mi Ẹ̀mí mi yíò wà pẹ̀lú yín. Èmi sì fún yín ní òfin kan pé kí ẹ̀yin ó ṣe àwọn ohun wọ̀nyí. Bí ẹ̀yin yíò bá sì ṣe wọ́n ní ìgbà gbogbo alábùkún-fún ni ẹ̀yin íṣe, nítorítí a ti kọ́ọ yín lé orí àpáta mi. Ṣùgbọ́n ẹnìkẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe ju èyí tàbí kí ó dín in kù, òun nã ni a kò kọ́ lé orí àpáta mi, ṣùgbọ́n a kọ́ọ lé orí ìpìlẹ̀ yanrìn; nígbàtí òjò sì rọ̀, tí ìkún omi sì dé, tí afẹ́fẹ́ sì fẹ́, tí wọn sì bìlù wọn, wọn yíò ṣubú, àwọn ẹnu-ọ̀nà ipò-òkú sì ti ṣí sílẹ̀ láti gbà wọ́n wọlé. Nítorínã alábùkún-fún ni ẹ̀yin íṣe bí ẹ̀yin bá pa òfin mi mọ́, èyítí Bàbá pàṣẹ pé kí èmi ó fi fún yín. Lóotọ́, lóotọ́, mo wí fún yín, ẹ níláti máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà-gbogbo, kí èṣù ó má bã dán yín wò, kí ó sì mú yín ní ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́bí èmi sì ti gbàdúrà lãrín yín bẹ̃ nã ni kí ẹ̀yin ó gbàdúrà nínú ìjọ mi, lãrín àwọn ènìyàn mi tí ó bá ronúpìwàdà àti tí a rìbọmi ní orúkọ mi. Ẹ kíyèsĩ èmi ni ìmọ́lẹ̀; èmi ti fi àpẹrẹ lélẹ̀ fún yín. Ó sì ṣe nígbàtí Jésù sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọnyĩ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀, ó tún yíjú padà sí àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ, lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, ẹ níláti máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà-gbogbo kí ẹ̀yin ó má bã bọ́ sínú ìdẹ́wò; nítorí Sátánì fẹ́ láti níi yín, kí ó lè kù yín bí àlìkámà. Nítorínã ẹ níláti máa gbàdúrà nígbà-gbogbo sí Bàbá ní orúkọ mi; Ohunkóhun tí ẹ̀yin yíò sì bẽrè lọ́wọ́ Bàbá ní orúkọ mi, èyítí ó yẹ, tí ẹ sì gbàgbọ́ pé ẹ ó rí gbà, ẹ kíyèsĩ a ó fí i fún yín. Ẹ máa gbàdúrà nínú ẹbí yín sí Bàbá, ní orúkọ mi nígbàgbogbo, kí àwọn aya yín àti àwọn ọmọ yín ó lè jẹ́ alábùkún-fún. Àti kí ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin yíò máa bá ara yín péjọ pọ̀ nígbàkũgbà; ẹ̀yin kò sì ní dá ẹnìkẹ́ni lẹ́kun láti wá sí ọ̀dọ̀ yín nígbàtí ẹ̀yin bá nbá ara yín péjọ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn ó wá sí ọ̀dọ̀ yín ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun; Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin ó gbàdúrà fún wọn, kí ẹ má sì ṣe lé wọn jáde; bí ó bá sì rí bẹ̃ tí wọn wá sí ọ̀dọ̀ yín nígbà-kũgbà ẹ̀yin ó máa gbàdúrà fún wọn sí Bàbá, ní orúkọ mi. Nítorínã, ẹ gbé ìmọ́lẹ̀ yín sókè kí ó lè tàn sí aráyé. Ẹ kíyèsĩ, èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa gbé sókè—èyítí ẹ̀yin ti rí tí èmi ṣe. Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ríi tí èmi ti gbàdúrà sí Bàbá, ẹ̀yin sì ti jẹ̃rí síi. Ẹ̀yin sì ríi pé èmi ti pàṣẹ pé kí ẹnìkẹ́ni nínú yín máṣe lọ, dípò èyí èmi pàṣẹ pé kí ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí ẹ̀yin ó fi ọwọ́ bá ojú ọgbẹ́ ara mi àti kí ẹ fi ojú ara yín rí mi; bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin ó ṣe fún aráyé; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì dá òfin yĩ kọjá ngba ara rẹ̀ lãyè fún fífà sínú ìdẹ́wò. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó tún yíjú rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọẹ̀hìn rẹ̀ àwọn tí ó ti yàn, ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ lóotọ́, lóotọ́, ni èmi wí fún yín, èmi fi òfin míràn fún yín, nígbànã ni èmi ó tọ Bàbá mi lọ kí èmi kí ó lè mú àwọn òfin míràn tí ó ti fún mi ṣẹ. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èyí ni òfin èyítí èmi fi fún yín, pé ẹ̀yin kì yíò jẹ́ kí ẹnìkẹ́ni kí ó bá yín pín nínú ara àti ẹ̀jẹ̀ mi ní àìpé, nígbàtí ẹ̀yin bá npín in fúnni; Nítorítí ẹnìkẹ́nì tí ó bá jẹ tí ó sì mu nínú ara àti ẹ̀jẹ̀ mi ní àìpé ni ó jẹ tí ó sì mu ìdálẹ́bi sí ẹ̀mí ara rẹ̀; nítorínã bí ẹ̀yin bá mọ̀ pé ẹnìkan wà ní àìpé láti jẹ àti láti mu nínú ara àti ẹ̀jẹ̀ mi kí ẹ̀yin kí ó dáa lẹ́kun. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ẹ̀yin kì yíò leè kúrò lãrín yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yíò jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún un ẹ̀yin yíò sì gbàdúrà fún un sí Bàbá, ní orúkọ mi; bí òun bá sì ronúpìwàdà tí a sì rĩbọmi ní orúkọ mi, nígbànã ni ẹ̀yin yíò gbã sí ãrin yín, tí ẹ̀yin yíò sì fún un nínú ara àti ẹ̀jẹ̀ mi. Ṣùgbọ́n bí òun kò bá ronúpìwàdà, a kò ní kã mọ́ àwọn ènìyàn mi, kí ó má bã pa àwọn ènìyàn mi run, nítorí ẹ kíyèsĩ mo mọ́ àwọn àgùtàn mi, a sì ti ka iye wọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ẹ̀yin kì yíò lé wọn kúrò nínú àwọn sínágọ́gù yín, tàbí àwọn ibi ìjọsìn yín, nítorítí irú àwọn bẹ̃ ni ẹ̀yin yíò tẹramọ́ láti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún; nítorí ẹ̀yin kò mọ̀ bóyá wọn yíò padà tí wọn yíò sì ronúpìwàdà, tí wọn yíò sì wá sí ọ̀dọ̀ mi tọkàn-tọkàn, tí èmi yìo sì wò wọ́n sàn; ẹ̀yin yíò sì jẹ́ ipa èyítí a fi mú ìgbàlà bá wọn. Nítorínã, kí ẹ̀yin kí ó pa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí èmi ti pa láṣẹ fún yín mọ́ kí ẹ̀yin ó máṣe gba ìdálẹ́bi; nítorí ègbé ni fún ẹnití Bàbá bá dálẹ́bi. Èmi sì fún yín ní àwọn òfin wọ̀nyí nítorí àwọn àríyànjiyàntí ó ti wà lãrín yín. Ìbùkún si ni fún yín bí kò bá sí àríyànjiyàn lãrín yín. Àti nísisìyí èmi nlọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá, nítorítí ó tọ̀nà pé kí èmi ó lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá nítorí yín. Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní sísọ, ó fi ọwọ́ rẹ kan àwọn ọmọ-ẹ̀hìn tí ó ti yàn ní ọ̀kọ̣́kan, àní títí ó fi fi ọwọ́ kan gbogbo wọn, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ bí ó ti nfi ọwọ́ kàn wọ́n. Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã kò sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó nsọ, nítorínã wọn kò ní àkọsílẹ̀ nípa wọn; ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã ní àkọsílẹ̀ pé ó fún wọn ní agbára láti fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni. Èmi yíò sì fi hàn yín tí ó bá yá pé òtítọ́ ni àkọsílẹ̀ yí jẹ́. Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti fi ọwọ́ kan gbogbo wọn tán, ikũku kan yọ tí ó sì ṣíjibo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã tí wọn kò lè rí Jésù. Bí a sì ti síjibò wọ́n, ó kúrò lãrín wọn, ó sì gòkè re ọ̀run. Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã sì ríi wọ́n sì jẹ̃rí síi pé ó tún gòkè re ọ̀run. 19 Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn méjìlá nã nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn nã wọ́n sì gbàdúrà fún gbígba Ẹ̀mí Mímọ́—A ṣe ìrìbomi fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã wọ́n sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì—Jésù gbàdúrà ó sì lo èdè tí ẹnìkẹ́ni kò lè kọ sílẹ̀—Ó jẹ̃rí sí ìgbàgbọ́ nlá tí ó tayọ ti àwọn ará Nífáì ní. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti gòkè re ọ̀run, àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã bá ọ̀nà ara wọn lọ, olúkúlukù sì mú ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ wọ́n sì padà sí ilé wọn. A sì kókìkí ìròyìn nã lãrín àwọn ènìyàn nã lójúkannã, kí ilẹ̀ ó tó ṣú, pé àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã ti rí Jésù, àti pé ó ti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn, àti pé òun yíò tún fi ara rẹ̀ hàn ní ọjọ́ kejì sí àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã. Bẹ̃ni, àti pẹ̀lú ní gbogbo òru ọjọ́ nã ni wọ́n kókìkí nípa ọ̀rọ̀ Jésù; wọn sì tan ọ̀rọ̀ nã ká tóbẹ̃ tí wọ́n pọ̀ tí ó tàn án ká, bẹ̃ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn, ni ó ṣiṣẹ́ takun-takun ní òru ọjọ́ nã, kí wọn ó lè wà níbití Jésù yíò gbé fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn ní ọjọ́ kejì. Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, nígbàtí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ pọ̀, ẹ kíyèsĩ, Nífáì àti arákùnrin rẹ̀ èyítí ó ti jí dìde kúrò nínú ipòòkú, ẹnití orúkọ rẹ̀ íṣe Tímótéù, àti ọmọkùnrin rẹ̀, ẹnití orúkọ rẹ̀ íṣe Jónà, àti Mátónì pẹ̀lú, àti Mátóníhà, arákùnrin rẹ̀, àti Kúménì, àti Kúménónhì, àti Jeremíàh, àti Ṣẹ́mnónì, àti Jónà, àti Sẹdẹkíàh, àti Isaiah—nísisìyí èyí ni orúkọ àwọn ọmọ-ẹ̀hin èyítí Jésù ti yàn—ó sì ṣe tí wọ́n jáde lọ tí wọ́n sì dúró lãrín àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã. Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã pọ̀ tó bẹ̃ tí wọ́n fi pín wọn sí ọ̀nà méjìlá. Àwọn méjìlá nnì sì kọ́ àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã ní ẹ̀kọ́; ẹ sì kíyèsĩ, wọ́n sì mú kí àwọn ènìyàn nã ó kúnlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé kí wọn ó sì gbàdúrà sí Bàbá ní orúkọ Jésù. Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã sì gbàdúrà sí Bàbá pẹ̀lú ní orúkọ Jésù. Ó sì ṣe tí wọ́n dìde tí wọ́n sì jíṣẹ́ ìránṣẹ́ lãrín àwọn ènìyàn nã. Nígbàtí wọ́n sì ti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ níti àwọn ọ̀rọ̀ kannã tí Jésù ti sọ—láìṣe àyípadà sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù ti sọ—ẹ kíyèsĩ, wọ́n tún kúnlẹ̀ wọ́n sì gbàdúrà sí Bàbá ní orúkọ Jésù. Wọ́n sì gbàdúrà fún ohun èyítí wọ́n fẹ́ jùlọ; wọ́n sì fẹ́ kí a fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún wọn. Nígbàtí wọ́n sì ti gbàdúrà ní ọ̀nà yĩ wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí etí omi nã, àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã sì tẹ̀lé wọn. Ó sì ṣe ti Nífáì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi nã tí a sì ṣe ìrìbọmi fũn. Ó sì jáde kúrò nínú omi nã, ó sì bẹ̀rẹ̀sí íṣe ìrìbọmi. Ó sì ṣe ìrìbọmi fun gbogbo àwọn ti Jésù ti yàn. Ó sì ṣe nígbàtí a ti ri gbogbo wọn bọmi tan ti wọ́n sì ti jáde kúrò nínú omi, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn, wọ́n sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti pẹ̀lú iná. Ẹ sì kíyèsĩ, ohun èyítí ó rí bí iná yí wọn ká; ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã sì jẹ̃rí síi, wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn ángẹ́lì sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá wọ́n sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ lãrín wọn. Ó sì ṣe bí àwọn ángẹ́lì nã ti nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ lãrín àwọn ọmọẹ̀hìn nã, ẹ kíyèsĩ, Jésù wá ó sì dúró lãrín wọn o si ṣiṣé ìránṣẹ́ sí wọn. Ó sì ṣe tí ó bá àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sọ̀rọ̀, ó sì paṣẹ fún wọn pé kí wọn ó tún kúnlẹ̀ lórí ilẹ̀, àti pẹ̀lú kí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ ó kúnlẹ̀ lórí ilẹ̀. Ó sì ṣe nígbàtí gbogbo wọn ti kúnlẹ̀ lórí ilẹ̀ tán, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pé kí wọn ó gbàdúrà. Ẹ sì kíyèsĩ, wọ́n bẹ̀rẹ̀sí gbàdúrà; wọ́n sì gbàdúrà sí Jésù, tí wọ́n sì npẽ ní Olúwa àti Ọlọ́run wọn. Ó sì ṣe tí Jésù jáde lọ kúrò lãrín wọn, ó sì rìn jìnà sí wọn díẹ̀ ó sì wolẹ̀ lé orí ilẹ̀, ó sì wípé: Bàbá, èmi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ìwọ ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn wọ̀nyí tí èmi ti yàn; nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú mi ni èmi sì ṣe yàn wọ́n kúrò nínú ayé. Bàbá, èmi gbàdúrà sí ọ kí ó fún gbogbo àwọn tí yíò gba ọ̀rọ̀ wọn gbọ́ ní Ẹ̀mí Mímọ́. Bàbá, ìwọ ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún wọn nítorípé wọ́n gbà mí gbọ́; ìwọ sì ríi pé wọ́n gbà mí gbọ́ nítorípé ó ngbọ́ wọn, wọ́n sì gbàdúrà sí mi; wọ́n sì gbàdúrà sí mi nítorípé mo wà lọ́dọ̀ wọn. Àti nísisìyí Bàbá, èmi gbàdúrà sí ọ nítorí wọn, àti nítorí gbogbo àwọn tí yíò gba ọ̀rọ̀ wọn gbọ́, kí wọn ó lè gbà mí gbọ́, kí èmi ó lè wà nínú wọn gẹ́gẹ́bí ìwọ, Bàbá, ti wà nínú mi, kí àwa ó lè jẹ́ ọ̀kan. Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti gbàdúrà sí Bàbá báyĩ tán, ó tọ àwọn ọmọ-ẹ̀hin rẹ̀ wá, ẹ sì kíyèsĩ, wọ́n sì tẹramọ́ gbígba àdúrà síi, láìsinmi; wọn kò sì lo ọ̀rọ̀ púpọ̀, nítorítí a ti fún wọn ní ohun tí wọn yíò gbàdúrà nípa rẹ̀, wọ́n sì kún fún ìbẽrè. Ó sì ṣe tí Jésù súre fún wọn bí wọn ti ngbàdúrà síi; ìwò rẹ sì fi ojú ãnú wò wọ́n, ìmọ́lẹ̀ ìwò rẹ̀ sì tàn sí wọn, ẹ sì kíyèsĩ wọ́n funfun bí ìwò Jésù àti bí ẹ̀wù Jésù pẹ̀lú; ẹ sì kíyèsĩ fífunfun yĩ tayọ fífunfun èyíkéyĩ, bẹ̃ni, àní kò sí ohunkóhun lórí ayé tí ó funfun tó fífunfun yìi. Jésù sì wí fún wọn pé: Ẹ tẹ̀síwájú nínú àdúrà gbígbà; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọn kò sì simi àdúrà gbígbà. Ó sì yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, ó sì kọjá lọ síwájú díẹ̀ ó sì wolẹ̀ sí órí ilẹ̀; ó sì tún gbàdúrà sí Bàbá, wípé: Bàbá, èmi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorítí ìwọ ti sọ àwọn tí èmi yàn di mímọ́, nítorí ìgbàgbọ́ wọn, èmi a sì máa gbàdúrà fún wọn, àti pẹ̀lú fún àwọn ti yíò gba ọ̀rọ̀ wọn gbọ́, kí a lè sọ wọ́n di mímọ́ nínú mi, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ wọn, àní bí a ti sọ wọn di mímọ́ nínú mi. Bàbá, èmi ngbàdúrà, kĩ ṣe fún aráyé, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ìwọ ti fifún mi láti inú ayé wá, nítorí ìgbàgbọ́ wọn, kí wọn ó lè di mímọ́ nínú mi, kí èmi ó lè wà nínú wọn gẹ́gẹ́bí ìwọ, Bàbá, ti wà nínú mi, kí àwa ó lè jẹ́ ọ̀kan, kí a lè ṣe mí lógo nínú wọn. Nígbàtí Jésù sì ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán ó tún padà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀; ẹ sì kíyèsĩ wọn ngbàdúrà ní ìtẹramọ́, láìsinmi, síi; ó sì tún fi ojú ãnú rẹ̀ wò wọ́n; ẹ sì kíyèsĩ wọ́n funfun, àní bí Jésù ṣe rí. Ó sì ṣe tí ó tún lọ síwájú díẹ̀ síi ó sì gbàdúrà sí Bàbá; Kò sì sí ahọ́n tí ó lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà tí ó gbà, bẹ̃ni ẹnìkẹ́ni kò lè kọ àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà tí ó gbà. Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã sì gbọ́ wọn sì jẹ̃rí síi; ọkàn wọn sì ṣí sílẹ̀ wọ́n sì ní ìmọ̀ nínú ọkàn wọn àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà tí ó gbà. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ọ̀rọ̀ àdúrà tí ó gbà nã jẹ́ nlá àti ìyanu tóbẹ̃ tí ẹnìkẹ́ni kò lè kọ wọ́n sílẹ̀, tàbí kí a sọ wọ́n. Ó sì ṣe nígbàtí Jésù parí àdúrà tí ó gbà ó tún padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã, ó sì wí fún wọn pé: Irú ìgbàgbọ́ tí ó tó èyí èmi kò ríi rí lãrín gbogbo àwọn Ju; nítorí-èyí ni èmi kò ṣe lè fi àwọn iṣẹ́ ìyanu nlá hàn wọ́n bí èmi ti fi hàn yín, nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Lóotọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹnìkẹ́ni nínú wọn tí ó rí àwọn ohun nlá irú èyí tí ẹ̀yin ti rí; bẹ̃ni wọn kò gbọ́ àwọn ohun nlá irú èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́. 20 Jésù pèsè àkàrà àti wáìnì ní ọ̀nà ìyanu ó sì tún fi àmì májẹ̀mú nã fún àwọn ènìyàn nã—Àwọn ìyókù Jákọ́bù yíò wá sí ìmọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn, wọn yíò sì jogún àwọn ilẹ̀ Amẹ́ríkà—Jésù ni wòlĩ nã bí Mósè, àwọn ará Nífáì sì ni àwọn irú-ọmọ wòlĩ nã—Àwọn tí íṣe ara àwọn ènìyàn Olúwa ni a ó kójọpọ̀ sí Jerúsálẹ́mù. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Ó sì ṣe tí ó pàṣẹ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã kí wọn ó simi àdúrà gbígbà, àti fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ nã. Ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó má simi àdúrà gbígbà nínú ọkàn wọn. Ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó dìde kí wọn ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn. Wọ́n sì dìde wọ́n sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn. Ó sì ṣe tí ó tún bù àkàrà ó sì súre síi, ó sì fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã kí wọn ó jẹ. Nígbàtí wọn sì ti jẹ ó pàṣẹ fún wọn láti bù àkàrà nã, kí wọn ó sì fifún àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã. Nígbàtí wọ́n sì ti fifún àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã tán ó fún wọn ní wáìnì kí wọn ó mu pẹ̀lú, ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó fifún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã pẹ̀lú. Nísisìyí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã kò mú àkàrà tàbí wáìnì wá, bẹ̃ni àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã kò mú wá; Ṣùgbọ́n nítọ́tọ́ ni ó fi àkàrà fún wọn jẹ, àti wáìnì fún wọnmu. Ó sì wí fún wọn pé: Ẹnití ó bá jẹ àkàrà yìi jẹ nínú ara mi fún ànfãní ẹ̀mí rẹ̀; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì mu nínú wáìnì yĩ mu nínú ẹ̀jẹ̀ mi fún ànfãní ẹ̀mí rẹ̀; ebi kò sì ní pa ẹ̀mí rẹ̀ tàbí kí òùngbẹ ó gbẹẹ́, ṣùgbọ́n yíò yó. Nísisìyí, nígbàtí gbogbo àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã ti jẹ tí wọ́n sì ti mu tán, ẹ kíyèsĩ, wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́; wọ́n sì kígbe pẹ̀lú ohùn kan, wọ́n sì fi ògo fún Jésù, ẹnití wọ́n rí àti tí wọ́n gbọ́. Ó sì ṣe nígbàtí gbogbo wọ́n ti fi ògo fún Jésù tán, ó wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ nísisìyí èmi ti parí òfin èyítí Bàbá ti pa laṣẹ fún mi nípa àwọn ènìyàn yĩ, àwọn tí íṣe ìyókù ìdílé Ísráẹ́lì. Ẹ̀yin rántí pé mo wí fún yín, tí mo sì wípé nígbàtí àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah yíò ṣẹ—ẹ kíyèsĩ a kọ wọ́n sílẹ̀, ẹ̀yin ní wọn níwájú yín, nítorínã ẹ gbé wọn yẹ̀wò— Àti lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, pé nígbàtí a ó mú wọn ṣẹ, nígbànã ni ìmúṣẹ májẹ̀mú tí Bàbá ti dá pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀, A! ìdílé Ísráẹ́lì. Nígbànã sì ni àwọn ìyókù nã, tí a ti fọ́nká kiri orí ilẹ̀ ayé, ni a ó kó wọn jọ láti ila ọ́run àti láti ìwọ ọ́run, láti gúsù àti láti àríwá; a ó sì mú wọn wá sínú ìmọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹnití ó ti rà wọ́n padà. Bàbá sì ti pàṣẹ fún mi pé kí èmi ó fi ilẹ̀ yí fún yín, fún ìní yín. Èmi sì wí fún yín, pé bí àwọn Kèfèrí kò bá ronúpìwàdà lẹ́hìn ìbùkún tí wọn yíò gbà, lẹ́hìn tí wọ́n ti fọ́n àwọn ènìyàn mi ká— Nígbànã ni ẹ̀yin, tí íṣe ìyókù ìdílé Jákọ́bù, yíò kọjá lọ lãrín wọn; ẹ̀yin yíò sì wà ní ãrin nwọn àwọn tí yio pọ̀ púpọ̀; ẹ̀yin yíò sì wà lãrín wọn bí kìnìún lãrín àwọn ẹranko igbó, àti bí ọmọ kìnìún lãrín àwọn agbo àgùtàn, èyítí, bí ó bá kọjá lãrín wọn, yíò tẹ̀ wọn mọ́lẹ̀, yíò tún fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kò sì sí ẹnití yíò gbà wọ́n là. A ó gbé ọwọ́ yín sókè sí órí àwọn ọ̀tá yín, gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sì ké kúrò. Èmi yíò sì kó àwọn ènìyàn mi jọ bí ènìyàn tií kó àwọn ìtì rẹ̀ sí ilẹ̀ ilé. Nítorítí èmi yíò ṣe àwọn ènìyàn mi àwọn ẹnití Bàbá ti bá dá májẹ̀mú, bẹ̃ni, èmi yíò ṣe ìwo yín ní irin, èmi yíò ṣe pátákó ẹsẹ̀ yín ní idẹ. Ẹ̀yin yíò sì fọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sí wẹ́wẹ́; èmi yíò sì yà ìkógun wọn sí mímọ́ fún Olúwa, àti ohun ìní wọn fún Olúwa gbogbo ayé. Ẹ sì kíyèsĩ, èmi ni ẹni nã tí ó ṣeé. Yíò sì ṣe, ni Bàbá wí, tí idà ododo mi yíò wà lórí wọn ní ọjọ́ nã; àti pé bí wọn kò bá ronúpìwàdà, yíò ṣubú lé wọn lórí, ni Bàbá wí, bẹ̃ni, àní lé orí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àwọn Kèfèrí. Yíò sì ṣe tí èmi yíò fi ìdí àwọn ènìyàn mi múlẹ̀, A! ìdílé Ísráẹ́lì. Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ènìyàn yĩ ni èmi yíò fi ìdí wọn múlẹ̀ ní ilẹ̀ yĩ, sí ìmúṣẹ májẹ̀mú èyítí èmi dá pẹ̀lú baba yín Jákọ́bù; yíò sì jẹ́ Jerúsálẹ́mù Titun. Àwọn agbára ọ̀run yíò sì wà lãrín àwọn ènìyàn yĩ; bẹ̃ni, àní èmi pãpã yíò wà lãrín yín. Ẹ kíyèsĩ, èmi ni ẹni nã tí Mósè sọ nípa rẹ̀, wípé: Olúwa Ọlọ́run yín yíò sì gbé wòlĩ kan sókè fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yíò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo èyíkeyĩ tí yíò sọ fún yín. Yíò sì ṣe tí olúkúlùkù ọkàn tí kò bá gbọ́ ti wòlĩ nã, òun ni a ó ké kúrò nínú àwọn ènìyàn. Lóotọ́ ni mo wí fún yín, bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn wòlĩ láti Sámúẹ̀lì wá, àti àwọn tí ó tẹ̀lée, iye àwọn tí ó ti sọ̀rọ̀, ni ó jẹ̃rí nípa mi. Ẹ sì kíyèsĩ, ẹyin ni àwọn ọmọ àwọn wòlĩ; irú-ọmọ ìdílé Ísráẹ́lì sì ni ẹ̀yin íṣe; àti ti májẹ̀mú èyítí Bàbá ti bá àwọn bàbá yín dá, nígbàtí ó wí fún Ábráhámù pé: Àti nínú irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo ìbátan ayé. Nígbàtí Bàbá ti jí mi dìde ni ó kọ́kọ́ rán mi sí ọ̀dọ̀ yín láti bùkúnfún yín nípasẹ̀ mímú olúkúlùkù yín kúrò nínú àwọn ìwà àìṣedẽdé yín; èyĩ sì rí bẹ̃ nítorípé ọmọ májẹ̀mú ni ẹ̀yin íṣe— Àti lẹ́hìn tí a tí bùkún fún yín nígbànã ni Bàbá mú májẹ̀mú nã ṣẹ èyítí ó ti bá Ábráhámù dá tí ó wípé: Nínú irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkúnfún gbogbo ìbátan ayé—sí ti fífúnni ní Ẹ̀mí Mímọ́ nípasẹ̀ mi sórí àwọn Kèfèrí, ìbùkún tí ó dà lórí àwọn Kèfèrí nã yíò mú wọn tóbi ju ènìyàn gbogbo, sí ti fífọn ká àwọn ènìyàn mi, A! ìdílé Ísráẹ́lì. Nwọn yíò sì jẹ́ pàṣán sí àwọn ènìyàn ilẹ̀ yĩ. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nígbàtí wọn bá ti gba ẹ̀kún ìhìn-rere mi, nígbànã bí wọn ó bá sì sé ọkàn wọn le mọ́ mi, èmi yíò dá àwọn ìwà àìṣedẽdé wọn padà sórí wọn, ni Bàbá wí. Èmi yíò sì rántí májẹ̀mú nã tí èmi ti dá pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi; èmi sì ti bá wọn dá májẹ̀mú pé èmi yíò kó wọn jọ ní àkokò tí ó tọ́ ní tèmi, tí èmi yíò tún padà fún wọn ní ilẹ̀ àwọn Bàbá wọn fún ìní wọn, èyítí íṣe ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, tí íṣe ilẹ̀ ìlérí nã fún wọn títí láé, ni Bàbá wí. Yíò sì ṣe tí àkokò nã yíò dé, nígbàtí a ó wãsù ẹ̀kún ìhìn-rere mi fún wọn; Wọn yíò sì gbà mí gbọ́, pé èmi ni Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, wọn yíò sì gbàdúrà sí Bàbá ní orúkọ mi. Nígbànã ni àwọn àlóre yíò gbé òhùn sókè, pẹ̀lú ohùn kan ni wọn yíò sì kọrin; nítorítí wọn yíò ríi ní ojúkojú. Nígbànã ni Bàbá yíò kó wọn jọ padà, tí yíò sì fi Jerúsálẹ́mù fún wọn ní ilẹ̀-ìní wọn. Nígbànã ni wọn yíò búsí ayọ̀—Ẹ jùmọ̀ kọrin, ẹ̀yin ibi ahoro Jerúsálẹ́mù; nítorítí Bàbá ti tù àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó ti ra Jerúsálẹ́mù padà. Bàbá ti fi apá rẹ̀ hàn ní ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; gbogbo àwọn ìkangun ayé ni yíò sì rí ìgbàlà Bàbá; Bàbá àti èmi sì jẹ́ ọ̀kan. Àti nígbànã ni a ó múu ṣẹ èyítí a kọ wípé: Jí, tún jí, kí ó sì gbé agbára rẹ wọ̀, A! Síónì; gbéaṣọ arẹwà rẹ wọ̀, A! Jerúsálẹ́mù, ìlú mímọ́, nítorí láti ìsisìyí lọ àwọn aláìkọlà àti àwọn aláìmọ́ kì yíò wọ inú rẹ mọ́. Gbọn ekuru kúrò ní ara rẹ; dìde, joko, A! Jerúsálẹ́mù; tú ara rẹ kúrò nínú ìdè ọrùn rẹ, A! òndè ọmọbìnrin Síónì. Nítorí báyĩ ni Olúwa wí: Ẹ̀yin ti ta ara yín lọ́fe, a ó sì rà yín padà láìsanwó. Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, pé àwọn ènìyàn mi yíò mọ́ orúkọ mi; bẹ̃ni, ní ọjọ́ nã wọn yíò mọ̀ pé èmi ni ẹnití nsọ̀rọ̀. Àti nígbànã ni wọn yíò wípé: Báwo ni ẹsẹ̀ ẹnití ó mú ìhìn-rere wá fún wọn ti dára tó lórí àwọn òkè gíga, ẹnití nkéde àlãfíà; tí ó sì mú ìhìn-rere wá fún àwọn ẹni dáradára, tí ó nkéde ìgbàlà; tí ó wí fún Síónì pé: Ọlọ́run rẹ njọba! Àti nígbànã ni igbe kan yíò jáde wá pé: Ẹ fà sẹ́hìn, ẹ fà sẹ́hìn, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, ẹ má fọwọ́kàn ohun àìmọ́; ẹ kúrò lãrín rẹ̀; ẹ jẹ́ mímọ́, ẹ̀yin tí ngbé ohun-èlò Olúwa. Nítorí ẹ̀yin kì yíò yára jáde, bẹ̃ni ẹ kì yíò fi ìsáré lọ; nítorítí Olúwa yíò ṣãjú yín, Ọlọ́run Ísráẹ́lì yíò sì tì yín lẹ́hìn. Ẹ kíyèsĩ, ìránṣẹ́ mi yíò fi òye bá ni lò; a ó gbée ga, a ó sì bù ọlá fún un, òun yíò sì ga lọ́pọ̀lọpọ̀. Gẹ́gẹ́bí ẹnu ti ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nípã rẹ—a bá ojú rẹ̀ jẹ́ ju ti ẹnìkẹ́ni lọ, àti ìrísí rẹ̀ ni a bàjẹ́ ju ti ọmọ ènìyàn lọ— Bẹ̃ni yíò bùwọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè; àwọn ọba yíò pa ẹnu wọn mọ́ síi, nítorípé wọn yíò rí ohun tí a kò sọ fún wọn; wọn yíò sì ní òye nípa èyítí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀. Lóotọ́, lóotọ́, mo wí fún yín, gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí ni yíò ṣẹ, àní gẹ́gẹ́bí Bàbá ti pàṣẹ fún mi. Nígbànã ni májẹ̀mú yĩ èyítí Bàbá ti dá pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ yíò di mímúṣẹ; àti nígbànã ni àwọn ènìyàn mi yíò tún máa gbé inú Jerúsálẹ́mù, yíò sì jẹ́ ilẹ̀ ìní wọn. 21 A ó kó Ísráẹ́lì jọ nígbàtí Ìwé ti Mọ́mọ́nì bá jáde wá—A ó fi àwọn Kèfèrí lélẹ̀ gẹ́gẹ́bí ènìyàn olómìnira ní Amẹ́ríkà—A o gbà wọn là bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì ṣe ìgbọràn; bíkòṣebẹ̃, a ó ké wọn kúrò a ó sì pa wọn run—Ísráẹ́lì yíò kọ́ Jerúsálẹ́mù Titun, àwọn ẹ̀yà tí ó ti sọnù yíò sì padà. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti lọ́tọ́ ni mo wí fún yín, èmi fún yín ní àmì kan, kí ẹ̀yin ó lè mọ́ àkokò nã tí àwọn ohun wọ̀nyí ti fẹ́rẹ̀ ṣẹlẹ̀—nígbàtí èmi yíò kó àwọn ènìyàn mi jọ, A! ìdílé Ísráẹ́lì, kúrò nínú ipò ìfọ́nká rẹ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́, tí èmi yíò sì tún padà fi ìdí Síónì mí mulẹ̀ lãrín nwọn. Ẹ sì kíyèsĩ, èyí ni ohun tí èmi yíò fifún ọ gẹ́gẹ́bí àmì—nítorí lóotọ́ ni mo wí fún yín, nígbàtí àwọn ohun wọ̀nyí tí èmi wí fún yín, àti tí èmi yíò tún wí fún yín lẹ́hìn èyí nípa ara mi, àti nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́ èyítí Bàbá yíò fi fún yín, yíò di mímọ̀ fún àwọn Kèfèrí kí wọn ó lè mọ̀ nípa àwọn ènìyàn tí íṣe ìyókùìdílé Jákọ́bù, àti nípa àwọn ènìyàn mi yìi tí wọn yíò fọ́nká. Lóotọ́, lóotọ́ ni mo wí fún yín, nígbàtí àwọn ohun wọ̀nyí yíò di mímọ̀ sí wọn nípasẹ̀ Bàbá, tí yíò sì jáde wá nípasẹ̀ Bàbá, láti ọ̀dọ̀ wọn sí yín; Nítorítí ohun ọgbọ́n ni nínú Bàbá láti fi wọ́n lélẹ̀ nínú ilẹ̀ yí, kí a sì fi wọ́n lélẹ̀ gẹ́gẹ́bí ènìyàn olómìnira nípa agbára Bàbá, kí àwọn ohun wọ̀nyí ó lè jáde wá láti ọ̀dọ̀ wọn sí ọ̀dọ̀ ìyókù àwọn irú-ọmọ yín, kí májẹ̀mú Bàbá ó lè di mímúṣẹ èyítí ó ti dá pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀, A! ìdílé Ísráẹ́lì; Nítorínã, nígbàtí àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí àti àwọn iṣẹ́ tí a ó ṣe lãrín yín lẹ́hìn èyí yíò jáde wá láti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí, sí àwọn irú-ọmọ yín tí wọn yíò rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ nítorí àìṣedẽdé; Nítorítí ó jẹ́ ìfẹ́ Bàbá pé kí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí jáde wá, kí òun lè fi agbára rẹ̀ hàn sí àwọn Kèfèrí, fún ìdí èyí, pe awọn Kèfèrí, bí wọn kò bá sé àyà wọn le, kí nwọn ó lè ronúpìwàdà kí wọn ó sì wá sí ọ̀dọ̀ mi kí a sì ṣe ìrìbọmi fún wọn ní orúkọ mi kí wọn ó sì mọ́ àwọn òtítọ́ ìlànà ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí a lè kà wọ́n mọ́ àwọn ènìyàn mi, A! ìdílé Ísráẹ́lì; Nígbàtí àwọn ohun wọ̀nyí bá sì ti ṣẹ tí àwọn irú-ọmọ yín sì bẹ̀rẹ̀sí mọ́ àwọn ohun wọ̀nyí—yíò jẹ́ ohun àmì fún wọn, kí wọn ó lè mọ̀ pé iṣẹ́ Bàbá ti bẹ̀rẹ̀ láti lè mú májẹ̀mú nnì ṣẹ èyítí ó ti dá pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí íṣe ìdílé Ísráẹ́lì. Nígbàtí ọjọ́ nã yíò sì dé, yíò sì ṣe tí àwọn ọba yíò pa ẹnu wọn mọ́; nítorípé wọn ó rí ohun tí a kò sọ fún wọn nípa rẹ̀; wọn yíò sì ní òye nípa èyítí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀. Nítorítí ní ọjọ́ nã, nítorí mi ni Bàbá yíò ṣe iṣẹ́ kan, èyítí yíò jẹ́ iṣẹ́ títóbi àti ìyanu lãrín wọn; a ó sì rí nínú wọn tí kò jẹ́ gba iṣẹ́ nã gbọ́, bí ẹnìkan tilẹ̀ sọ̣́ fún wọn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀mí ìránṣẹ́ mi yíò wà ní ọwọ́ mi; nítorínã wọn kò lè pã lára, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé a ó bã jẹ́ nítorí wọn. Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yíò wọ́ sàn, nítorítí èmi yíò fihàn wọ́n pé ọgbọ́n mi tóbi ju ọgbọ́n-àrékérekè èṣù lọ. Nítorínã yíò sì ṣe, ẹnìkẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, pé èmi ni Jésù Krístì, èyítí Bàbá yíò mú kí ó mú jáde tọ àwọn Kèfèrí lọ, tí yíò sì fún un ní agbára láti mú wọn jáde tọ àwọn Kèfèrí lọ, (a ó ṣeé gẹ́gẹ́bí Mósè ti sọ) a ó ké wọn kúrò lãrín àwọn ènìyàn mi tí wọ́n wà nínú májẹ̀mú nã. Àwọn ènìyàn mi tí íṣe ìyókù ìdílé Jákọ́bù yíò sì wà lãrín àwọn Kèfèrí, bẹ̃ni, lãrín wọn bí kìnìún lãrín àwọn ẹranko igbó, àti bí ọmọ kìnìún lãrín àwọn agbo àgùtàn, èyítí, bí ó bá kọjá lãrín wọn, yíò tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, yíò tún fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kò sì sí ẹnití yíò gbà wọ́n là. A ó gbé ọwọ́ wọn sókè sí órí àwọn ọ̀tá wọn, gbogbo àwọn ọ̀tá wọn ni a ó sì ké kúrò. Bẹ̃ni, ègbé ni fún àwọn Kèfèrí bíkòṣe pé wọn ronúpìwàdà; nítorí yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã, ni Bàbá wí, tí èmi yíò ké àwọn ẹṣin yín kúrò lãrín yín, èmi yíò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin yín run; Èmi yíò sì ké àwọn ìlú-nlá inú ilẹ̀ yín kúrò, èmi ó sì bi gbogbo àwọn ibi gíga yín lulẹ̀; Èmi yíò sì ké gbogbo ìṣe-oṣó kúrò nínú ilẹ̀ yín, ẹ̀yin kì yíò sì ní àwọn aláfọ̀ṣẹ mọ́; Àwọn ère fífín yín pẹ̀lú ni èmi ó ké kúrò, àti àwọn ère yín ni èmi ó ké kúrò lãrín rẹ̀, ẹ̀yin kì ó sin iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mọ́; Èmi ó sì fa àwọn igbó sũrù yín tu kúrò lãrín yín; bákannã ni èmi yíò pa àwọn ìlú-nlá yín run. Yíò sì ṣe tí gbogbo irọ́-pípa àti ẹ̀tàn gbogbo, àti ìlara, àti ìjà, àti àwọn iṣẹ́ àlùfã alárèkérekè, àti àwọn ìwà-àgbèrè, ni a ó mú kúrò. Nítorítí yíò sì ṣe, ni Bàbá wí, pé ní ọjọ́ nã ẹnìkẹ́ni tí kò bá ronúpìwàdà kì ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Àyànfẹ́ Ọmọ mi, àwọn ni èmi yíò ké kúrò lãrín àwọn ènìyàn mi, A! ìdílé Ísráẹ́lì; Èmi yíò sì gbẹ̀san ní ìbínú lori nwọn, ani gẹgẹbi lori awọn aboriṣa, irú èyítí wọn kò gbọ́ rí. Ṣùgbọ́n bí wọn ó bá ronúpìwàdà tí wọ́n sì fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi, tí wọn kò sì sé ọkàn wọn le, èmi yíò fi ìjọ mi lélẹ̀ lãrín wọn, wọn yíò sì dá májẹ̀mú nã a ó sì kà wọn mọ́ àwọn ìyókù ìdílé Jákọ́bù, àwọn tí èmi ti fi ilẹ̀ yĩ fún ní ìní fún wọn; Wọn yíò sì ran àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́, àwọn ìyókù ìdílé Jákọ́bù, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ìdílé Ísráẹ́lì tí yíò bá wá, kí wọn ó lè kọ́ ìlú-nlá kan, èyítí a ó pè ní Jerúsálẹ́mù Titun. Àti nígbànã ni wọn yíò ran àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́ kí àwọn tí a ti fọ́nká kiri gbogbo orí ilẹ̀ nã lè di kíkójọ pọ̀ sínú Jerúsálẹ́mù Titun. Àti nígbànã ni agbara ọrun yíò sọ̀kalẹ̀ sí ãrin wọn; èmi pãpã yíò sì wà lãrín wọn. Àti nígbànã ni iṣẹ́ Bàbá yíò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ nã, àní nígbàtí a ó wãsù ìhìn-rere yĩ lãrín àwọn ìyókù àwọn ènìyàn yĩ. Lóotọ́ ni mo wí fún yín, ní ọjọ́ nã ni iṣẹ́ Bàbá yíò bẹ̀rẹ̀ lãrín gbogbo àwọn ènìyàn mi tí ó fọ́nká, bẹ̃ni, àní àwọn ẹ̀yà tí ó sọnù, tí Bàbá ti darí jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Bẹ̃ni, iṣẹ́ nã yíò bẹ̀rẹ̀ lãrín gbogbo àwọn ènìyàn mi tí ó fọ́nká, pẹ̀lú Bàbá tí yíò palẹ̀ ọ̀nà mọ́ èyítí wọn ó gbà wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí wọn ó lè ké pe Bàbá ní orúkọ mi. Bẹ̃ni, nígbànã sì ni iṣẹ́ nã yíò bẹ̀rẹ̀, pẹ̀lú Bàbá lãrín orílẹ̀-èdè gbogbo fún pípalẹ̀ ọ̀nà mọ́ nínú èyítí a ó gbà láti kó àwọn ènìyàn rẹ̀ wọlé lọ sí ìlẹ̀ ìní wọn. Wọn yíò sì jáde lọ láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo; wọn kì yíò yára jáde, bẹ̃ni wọn kì yíò fi ìkánjú lọ, nítorí èmi yíò ṣãjú wọn, ni Bàbá wí, èmi yíò sì tì wọn lẹ́hìn. 22 Ní ọjọ́-ìkẹhìn, a ó fi ìdí Síónì àti àwọn ẽkàn rẹ múlẹ̀, a ó sì kó Ísráẹ́lì jọ nínú ãnú àti ìkẹ́—Wọn yíò borí—A fi órí ìwé yĩ wé Isaiah 54. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọOlúwa wa. Nígbànã sì ni èyítí a kọ sílẹ̀ yíò ṣẹ: Kọrin, A! ìwọ àgàn, ìwọ tí kò bí rí; bú sí orin, sì ké rara, ìwọ tí kò rọbí rí; nítorí àwọn ọmọ ẹni-ahoro pọ̀ ju àwọn ọmọ ẹnití a gbé ní ìyàwó, ni Olúwa wí. Sọ ibi àgọ́ rẹ di gbígbọ́rò, sì jẹ́ kí wọn na aṣọ ìbòjú inú àgọ́ ibùgbé rẹ; máṣe dá-sí, sọ okùn rẹ di gígùn, kí ó sì mú ẽkàn rẹ le; Nítorítí ìwọ ó yà sí apá ọ̀tún àti sí apá òsì, irú-ọmọ rẹ yíò sì jogún àwọn Kèfèrí tí wọn ó sì mú kí àwọn ìlú ahoro wọnnì di ibi gbígbé. Máṣe bẹ̀rù, nítorí ojú kì yíò tì ọ́; bẹ̃ni kí o máṣe dãmú, nítorí a kì yíò dójú tì ọ́; nítorí ìwọ ó gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ, ìwọ kì yíò sì rántí ẹ̀gàn ìgbà èwe rẹ, ìwọ kò sì ní rántí ẹ̀gàn ìgbà-opó rẹ mọ́. Nítorí ẹlẹ́da rẹ, ọkọ rẹ, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀, àti Olùràpadà rẹ, Ẹní Mímọ́ Ísráẹ́lì—Ọlọ́run àgbáyé ni a ó máa pẽ. Nítorí Olúwa ti pè ọ́ bí obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀, tí a sì bà nínú jẹ́, àti bí aya ìgbà èwe, nígbàtí a ti kọ̣́ ni Ọlọ́run rẹ wí. Ní ìṣẹ́jú díẹ̀ ni mo ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n nínú ãnú nlá ni èmi ó kó ọ jọ. Nínú ìbínú díẹ̀ ni èmi pa ojú mi mọ́ kúrò lára rẹ ní ìṣẹ́jú díẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú inú-rere tí ó wà títí ayé ni èmi ó fi ṣãnú fún ọ, ni Olúwa Olùràpadà rẹ wí. Nítorí bí omi Nóà ni èyí rí sí mi, nítorí gẹ́gẹ́bí mo ti búra pé omi Nóà kì yíò bò ayé mọ́, bákannã ni mo ti bura pe èmi kì yíò bínú sí ọ. Nítorí àwọn òkè-gíga yíò ṣí kúrò, a ó sì ṣí àwọn òkè kékèké ní ìdí, ṣùgbọ́n inú rere mi kì yíò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ̃ni èmi kì yíò ṣí májẹ̀mú àlãfíà mi ní ipò, ni Olúwa ẹnití ó ṣãnú fún ọ wí . A! ìwọ ẹnití à npọ́n lójú, tí a sì nfi agbara bí ìjì nlá gbá kiri, tí a kò sì tù nínú! Kíyèsĩ, èmi ó fi òkúta aláwọ̀ aláràbarà lélẹ̀ fun ọ, èmi ó sì fi òkúta sàfírà ṣe ìpìlẹ̀ rẹ. Èmi yíò si fi agate ṣe fèrèsé rẹ, èmi ó sì fi òkúta iyebíye dídán ṣe ilẹ̀kùn rẹ, èmi ó sì fi òkúta àṣàyàn ṣe agbègbè rẹ. Olúwa yíò sì kọ́ gbogbo àwọn ọmọ rẹ; àlãfíà àwọn ọmọ rẹ yíò sì pọ̀. Nínú òdodo ni a ó fi ìdí rẹ múlẹ̀; ìwọ jìnà sí ìnira nítorítí ìwọ kì yíò bẹ̀rù, àti pẹ̀lú ìwọ ó jìnà sí ìfòyà nítorí kì yíò súnmọ́ ọ. Kíyèsĩ, ní kíkójọ wọn ó kó ara wọn jọ dojúkọ ọ́, kĩ ṣe nípasẹ̀ mi; ẹnìkẹ́ni tí ó bá kó ara wọn jọ dojúkọ ọ́ yíò ṣubú nítorí rẹ. Kíyèsĩ, èmi ni ẹnití ó dá alágbẹ̀dẹ tí nfẹ́ ẹyin-iná, tí ó sì ńrọ irin-iṣẹ́ fún iṣẹ́ ara rẹ̀; èmi sì ni ẹnití ó dá apanirun láti panirun. Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yíò lè ṣe rere; àti gbogbo ahọ́n tí yíò pẹ̀gàn rẹ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi. Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, láti ọ̀dọ̀ mi ni òdodo wọn ti wá, ni Olúwa wí. 23 Jésù fi inúdídùn rẹ̀ hàn sí àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah—Ó pàṣẹ kí àwọn ènìyàn nã ó ṣe ìwãdí ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ—Àwọn ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì ará Lámánì nípa Àjĩnde Jésù ni à fikún àwọn àkọsílẹ̀ wọn. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín, pé kí ẹ̀yin ó ṣe ìwãdí àwọn ohun wọ̀nyí. Bẹ̃ni, mo pãláṣẹ fún yín pé kí ẹ̀yin ó wãdí àwọn ohun wọ̀nyí tọkàn-tara; nítorí títóbi ni àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah. Nítorí dájúdájú ni ó sọ nípa ohun gbogbo nípa àwọn ènìyàn mi tí íṣe ti ìdílé Ísráẹ́lì; nítorínãó di dandan pé kí ó bá àwọn Kèfèrí nã sọ̀rọ̀. Ohun gbogbo tí ó sì ti sọ ni ó ti rí bẹ̃, wọn yíò sì rí bẹ̃, àní ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ nã ti ó sọ. Nítorínã ẹ ṣe ìgbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ mi; ẹ kọ àwọn ohun tí mo ti wí fún yín sílẹ̀; wọn yíò sì tọ àwọn Kèfèrí lọ ní ìbámu pẹ̀lú àkokò àti ìfẹ́ Bàbá. Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi tí ó sì ronúpìwàdà tí a sì ṣe iribọmi fun, òun nã ni a ó gbàlà. Ẹ máa ṣe ìwãdí àwọn wòlĩ, nítorípé wọ́n pọ̀ tí ó ṣe ìjẹ́rísí àwọn ohun wọ̀nyí. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wonyĩ tán ó tún wí fún wọn, lẹ́hìn tí ó ti sọ àsọyé fún wọn lórí àwọn ọ̀rọ̀ ìwé-mímọ́ tí wọ́n ti gbà, ó wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó kọ àwọn ìwé-mímọ́ míràn sílẹ̀, èyítí ẹ̀yin kò ì kọ. Ó sì ṣe tí ó wí fún Nífáì pé: Mú àwọn àkọsílẹ̀ tí ẹ ti kọ wá. Nígbàtí Nífáì sì ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nã wá, tí ó sì gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wò wọn ó sì wípé: Lóotọ́ ni mo wí fún yín, mo pàṣẹ fún ìránṣẹ́ mi Sámúẹ́lì, ará Lámánì, pé kí ó ṣe ìjẹ́rĩ sí fún àwọn ènìyàn yìi, pé ní ọjọ́ nã tí Bàbá yíò ṣe orúkọ rẹ̀ lógo nínú mi, pé àwọn ènìyàn mímọ́ púpọ̀ ni yíò jí dìde kúrò nínú ipò-òkú, tí wọn yíò sì farahàn sí àwọn ènìyàn púpọ̀, tí wọn yíò sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ lãrín wọn. Ó sì wí fún wọn pé: Njẹ́ kò ha rí bẹ̃ bí? Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ sì dáa lóhùn wọ́n sì wípé: Bẹ̃ni, Olúwa, Sámúẹ́lì ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ, gbogbo wọn ni ó sì ti ṣẹ. Jésù sì wí fún wọn pé: Báwo ni ẹ̀yin kò ṣe tĩ kọ eleyĩ, pé àwọn ènìyàn mímọ́ púpọ̀ ni ó jí dìde kúrò nínú ipò-òkú tí wọ́n sì farahàn sí àwọn ènìyàn púpọ̀ ti wọ́n sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ lãrín wọn? Ó sì ṣe tí Nífáì rántí pé wọn kò ì kọ eleyĩ. Ó sì ṣe tí Jésù pàṣẹ pé kí wọn ó kọọ́; nítorínã ni wọ́n kọọ́ gẹ́gẹ́bí ó ti pãláṣẹ. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àsọyé fún wọn lórí àwọn ìwé-mímọ́ nã lápapọ̀, èyítí wọ́n ti kọ, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ nípa àwọn ohun tí òun ti sọ àsọyé lórí wọn. 24 Oníṣẹ Olúwa yíò tún ọ̀nà ṣe fún Bíbọ̀ kejì—Krístì yíò joko ní ìdájọ́—A pàṣẹ fún Ísráẹ́lì lati san ìdámẹ̃wá àti ọrẹ—A kọ ìwé ìrántí—A fi orí ìwé yĩ wé Málákì 3. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Ó sì ṣe tí ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí Bàbá ti fifún Málákì, èyítí òun yíò sọ fún wọn. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí wọn ti kọọ́ tán ó sọ àsoyé lórí wọn. Èyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ nã tí ó sọ fún wọn, wípé: Báyĩ ni Bàbá wí fún Málákì—Kíyèsĩ, èmi yíò rán oníṣẹ́ mi, yíò sì tún ọ̀nà ṣe níwájú mi, Olúwa tí ẹ̀yin sì nwá yíò dé ní òjijì sí tẹ́mpìlì rẹ̀, àní oníṣẹ́ májẹ̀mú nã, ẹnití inú yín dùn sí; ẹ kíyèsĩ, oun yíò wá, ni Olúwa àwọn Ọmọogun wí. Ṣùgbọ́n tani ó lè gbà ọjọ́ wíwá rẹ̀, tani yíò sì dúró nígbàtí ó báfi ara hàn? Nítorítí ó dàbí iná ẹnití ndà fàdákà, àti bí ọṣẹ afọṣọ. Òun yíò sì joko bí ẹnití nyó àti ẹnití ndà fàdákà; òun yíò sì ṣe àwọn àtẹ̀lé ọmọ Léfì ní mímọ́, yíò sì yọ wọn bí wúrà òun fàdákà, kí wọn kí ó lè rú ẹbọ òdodo sí Olúwa. Nígbànã ni ọrẹ Júdà àti ti Jerúsálẹ́mù yíò wu Olúwa gẹ́gẹ́bí ọjọ́ ti ìgbà àtijọ́, àti gẹ́gẹ́bí ọdún ti àtijọ́. Èmi ó sì súnmọ́ ọ láti ṣe ìdájọ́; èmi yíò sì ṣe ẹlẹri ní kánkán sí àwọn oṣó, àti sí àwọn panṣágà, àti sí àwọn abúra èké àti àwọn tí ó ni alágbàṣe lára nínú owó ọya rẹ̀, àti opó, àti aláìníbàbá, àti sí ẹnití ó kọ̀ láti ran àjèjì lọ́wọ́, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí. Nítorí èmi ni Olúwa, èmi kò yípadà; nítorínã ni a kò ṣe run ẹ̀yin ọmọ Jákọ́bù. Àní láti ọjọ́ àwọn bàbá yín wá ni ẹ̀yin ti yapa kúrò nínú ìlànà mi, tí ẹ kò sì pa wọ́n mọ́. Ẹ yípadà sí ọ̀dọ̀ mi, èmi o sì yípadà sí ọ̀dọ̀ yín, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wípé: Nípa báwo ni àwa ó yipadà? Ènìyàn yíò ha ja Ọlọ́run ní olè bí? Síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mií ní ólè. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wípé: Nípa báwo ni àwa fi jà ọ́ ní olè? Nípa ìdámẹ̃wá àti ọrẹ. A ti fi yín bú, nítorí ẹ̀yin ti jà mí ní ólè, àní gbogbo orílè-èdè yĩ. Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wá wá sí ilé ìṣura, kí oúnjẹ ó lè wà ní ilé mi; ẹ sì fi èyí dán mi wò nísisìyí, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, bí èmi kì yíò bá ṣí fèrèsé ọ̀run fún yín, kí èmi ó sì tú ìbùkún jáde fún yín, tóbẹ̃ tí kì yíò sí àyè láti gbã. Èmi ó sì bá ajẹnirun wí nítorí yín, òun kì ó sì run èso ilẹ̀ yín; bẹ̃ni àjàrà yín kì yìó rẹ̀ dànù ní àìpé ọjọ́ nínú oko, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí. Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yíò sì pè yín ní alábùkún fún, nítorípé ẹ̀yin ó jẹ́ ilẹ̀ tí ó wunni, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí. Àwọn ọ̀rọ̀ yín jẹ́ líle sí mi, ni Olúwa wí. Síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀yin wípé: Ọ̀rọ̀ kíni àwa sọ sí ọ? Ẹ̀yin ti wípé: Asán ni láti sin Ọlọ́run, ànfàní kíni ó sì jẹ́, tí àwa ti pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́, tí àwa ti rìn nínú ìrora-ọkàn níwájú Olúwa àwọn Ọmọ-ogun? Àti nísisìyí àwa pe agbéraga ní onínúdídùn; bẹ̃ni, àwọn tí ó nṣe búburú npọ̀ síi; bẹ̃ní, àwọn tí ó dán Ọlọ́run wò sã ni a dá sí. Nígbànã ni àwọn t í ó bẹ̀rù Olúwa nbá ara wọn sọ̀rọ̀ nígbàkũgbà, Olúwa sì fetísílẹ̀, ó sì gbọ́; a sì kọ ìwé-ìrántí kan níwájú rẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa, tí wọ́n sì nrántí, tí wọ́n sì bẹ̀rù orúkọ rẹ̀. Wọn yíò sì jẹ́ tèmi, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, ní ọjọ́ nã nígbàtí èmi ó kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ mi jọ; èmi ó sì dá wọn sí gẹ́gẹ́bí ènìyàn íti máa dá ọmọ rẹ̀ tí ó nsìn í sí. Nígbànã ni ẹ̀yin ó padà, tí ẹ ó sì mọ́ ìyàtọ̀ lãrín olódodo àti ẹni-búburú, lãrín ẹnití nsin Ọlọ́run àti ẹnití kò sìn ín. 25 Ní àkokò Bíbọ̀ kejì, a ó jó gbogboàwọn agbéraga àti àwọn olùṣe búburú níná bí àkékù koríko—Èlíjàh yíò padà wá kí ọjọ́ nlá èyítí ó ní ẹ̀rù nã ó tó dé—A fi orí ìwé yìi wé Málákì 4. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Nítorí ẹ kíyèsĩ, ọjọ́ nbọ̀ èyítí ó rí bí iná ìléru, àti tí yíò jó gbogbo àwọn agbéraga, bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn olùṣe búburú, yíò dàbí àkékù koríko; ọjọ́ nã tí nbọ̀ yíò sì jó wọn run, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, tí kì yíò fi ku gbòngbò tàbí ẹ̀ka fún wọn. Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, ni Ọmọ Òdodo nã yíò dìde pẹ̀lú ìmúláradá ní ìyẹ́ apá rẹ̀; ẹ̀yin ó sì jáde lọ, ẹ̀yin ó sì máa dàgbà bí àwọn ẹgbọrọ màlũ inú agbo. Ẹ̀yin ó sì tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀; nítorí wọn ó já sí eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ nã tí èmi yíò ṣe ohun yĩ, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí. Ẹ rántí òfin Mósè ìránṣẹ́ mi, èyítí mo pa ní àṣẹ fún un ní Hórébù fún gbogbo Ísráẹ́lì, pẹ̀lú àwọn ìlànà àti ìdájọ́ wọnnì. Kíyèsĩ, èmi yíò rán wòlĩ Èlíjàh sí yín kí ọjọ́ Olúwa nã èyítí íṣe nlá tí ó sì ní ẹ̀rù tó dé. Òun yíò sì yí ọkàn àwọn bàbá padà sí ti àwọn ọmọ wọn, àti ọkàn àwọn ọmọ sí ti àwọn bàbá wọn, kí èmi kí ó má bá wá kí èmi ó sì fi ayé bú. 26 Jésù sọ àsọyé lórí ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ wá títí dé òpin—Àwọn ọmọ ọwọ́ àti àwọn ọmọdé sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó yani lẹ́nu tí a kò lè kọ—Àwọn tí ó wà nínú Ìjọ Krístì jùmọ̀ ní ohun gbogbo. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán ó sọ àsọyé lórí wọn fún àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã; ó sì tún sọ àsọyé lórí ohun gbogbo fún wọn, lórí ohun tí ó tóbi àti kékeré. Ó sì wí pé: Àwọn ìwé-mímọ́ wọ̀nyí, èyítí ẹ̀yin kò ní, Bàbá pàṣẹ pé kí èmi ó fifún yín; nítorítí ohun ọgbọ́n ni nínú rẹ̀ pé kí a fifún àwọn ìran tí nbọ̀ lẹ́hìn-ọ̀la. Ó sì sọ àsọyé lórí ohun gbogbo, àní láti ìbẹ̀rẹ̀ wá títí dé àkokò tí yíò wá nínú ògo rẹ̀—bẹ̃ni, àní ohun gbogbo tí yíò ṣẹ ní orí ilẹ̀ ayé, àní títí àwọn iṣẹ́ inú rẹ̀ yíò di yíyọ́ nítorí àwọn ọ́ru tí ó gbóná, tí àwọn ọ̀run àti ayé yíò kọjá lọ; Àti pãpã títí dé ọjọ́ nlá èyítí ó kẹ́hìn, nígbàtí ènìyàn gbogbo, àti gbogbo ìbátan, àti orílẹ̀-èdè gbogbo, àti gbogbo èdè, yíò dúró níwájú Ọlọ́run fún ìdájọ́ lórí iṣẹ́ wọn, bóyá rere ni wọ́n tàbí bóyá búburú ni wọn íṣe— Bí wọ́n bá jẹ́ rere, sí àjínde ìyè àìlópin; bí wọ́n bá sì jẹ́ búburú, sí àjínde sí ìdálẹ́bi; nítorítí wọ́n wà ní ọ̀tọ̀, tí ọ̀kan wà ní apá kan, tí èkejì sì wà ní apá kejì, gẹ́gẹ́bí ãnú, àti àìṣègbè, àti ìwà mímọ́ èyítí ó wà nínú Krístì, ẹnití ó ti wà ṣãjú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Àti nísisìyí èmi kò lè kọ ìdá kan nínú ọgọ́run sí inú ìwé yĩ nínú àwọn ohun tí Jésù kọ́ àwọn ènìyàn yĩ ní tọ́tọ́; Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àwọn àwo Nífáì ni ó ní púpọ̀ nínú àwọn ohun tí ó kọ àwọn ènìyàn nã; Àwọn ohun wọ̀nyí sì ni èmi sì ti kọ, tí ó jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn ohun tí ó kọ́ àwọn ènìyàn nã; èmi sì kọ wọ́n kí a lè tún mú wọn wá fún àwọn ènìyàn yĩ, láti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ti Jésù ti sọ. Nígbàtí wọ́n bá sì ti rí èyí gbà tán, èyítí ó tọ̀nà, pé kí wọn ó kọ́kọ́ gbà, láti dán ìgbàgbọ́ wọnwò, bí ó bá sì rí bẹ̃ tí wọ́n sì gba ohun wọ̀nyí gbọ́, nígbànã ni a ó fi àwọn ohun púpọ̀ tí a ti kọ nã hàn sí wọn. Bí ó bá sì rí bẹ̃ tí wọn kò bá gba àwọn ohun wọ̀nyí gbọ́, nígbànã ni a ó fi àwọn ohun púpọ̀ nã tí a ti kọ pamọ́ fún wọn, sí ìdálẹ́bi fún wọn. Ẹ kíyèsĩ, mo ti ṣetán láti kọ wọ́n, gbogbo àwọn ohun tí àwọn wòlĩ ti fín sí orí àwọn àwo Nífáì, ṣùgbọ́n Olúwa dá mi lẹ́kun, ó wípé: Èmi yíò dán ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn mi wò. Nítorínã ni èmi, Mọ́mọ́nì, kọ àwọn ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ fún mi. Àti nísisìyí èmi, Mọ́mọ́nì, mú ọ̀rọ̀ mi wá sí òpin, èmi sì tẹ̀síwájú láti kọ àwọn ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ fún mi. Nítorínã, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó ríi pé Olúwa kọ́ àwọn ènìyàn yĩ ní tọ́tọ́, fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta; lẹ́hìnnã ó sì nfi ara rẹ̀ hàn sí wọn nígbàkũgbà, ó sì nbu àkàrà nígbàkũgbà, ó súre síi, ó sì nfifún wọn. Ó sì ṣe tí ó nkọ́ àwọn ọmọ àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã lẹkọ, tí ó sì ṣiṣẹ́-ìránṣẹ́ lãrín wọn, àwọn tí a ti sọ̀rọ̀ nípa wọn, ó sì là wọ́n ní ohùn, wọ́n sì sọ àwọn ohun nlá tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn bàbá wọn, àní àwọn ohun tí ó tóbi ju èyítí ó ti fi han àwọn ènìyàn nã; ó sì là wọ́n ní ohùn kí wọn ó lè sọ̀rọ̀. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí ó ti gòkè re ọ̀run—ní ìgbàkejì ti ó ti fi ara rẹ̀ hàn wọ́n, àti tí ó sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá, lẹ́hìn tí ó ti wo àwọn aláìsàn wọn, àti àwọn arọ wọn, àti tí ó la ojú àwọn afọ́jú wọn àti tí ó la etí àwọn adití, àti pãpã tí ó ti ṣe onírurú ìwòsàn lãrín wọn, àti tí ó ti jí ẹnìkan dìde kúrò nínú ipò-òkú, àti tí ó ti fi agbára rẹ̀ hàn sí wọn, tí ó sì ti gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá— Ẹ kíyèsĩ, ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì tí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã kó ara wọn jọ, tí wọ́n sì rí àti tí wọn gbọ́ àwọn ọmọdé wọ̀nyí; bẹ̃ni, àní àwọn ọmọ ọwọ́ sì la ẹnu wọn tí wọ́n sì sọ àwọn ohun ìyàlẹ́nu; àwọn ohun tí wọ́n sì sọ ni Olúwa dá wọn lẹ́kun kí ẹnìkẹ́ni ó máṣe kọ wọ́n. Ó sì ṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn tí Jésù ti yàn bẹ̀rẹ̀sí ńṣe ìrìbọmi láti ìgbà nã lọ àti láti kọ́ gbogbo àwọn tí ó bá tọ̀ wọ́n wá; àti gbogbo àwọn tí ó ṣe ìrìbọmi ní orúkọ Jésù ni ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni wọ́n sì rí àti tí ó gbọ́ àwọn ohun tí a kò lè sọ, èyítí a kò gbà wọ́n lãyè láti kọ. Wọ́n sì kọ́ ni lẹ́kò, wọ́n sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ara wọn; wọ́n sì jùmọ̀ ní ohun gbogbo lápapọ̀, olúkúlùkù sì nṣe èyítí ó tọ́ sí èkejì rẹ̀. O sì ṣe tí wọn ṣe ohun gbogbo àní gẹ́gẹ́bí Jésù ti palaṣẹ fun wọn. Àwọn tí a sì ṣe ìrìbọmi fun ní orúkọ Jésù ni a pè ní ìjọ Krístì. 27 Jésù pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó pe Ìjọ nã ní orúkọ òun—Iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ẹbọ-ọrẹ ètùtù rẹ̀ jẹ́ ìhìn-rere rẹ̀—A pàṣẹ fún àwọn ènìyàn kí wọn ó ronúpìwàdà kí a sì ṣe ìrìbọmi fun wọn ki a bá lè yà wọ́n sí mímọ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́—Wọ́n níláti rí bí Jésù ti rí pãpã. Ní ìwọ̀n ọdún 34 sí 35 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Ó sì ṣe bí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù ti nrin ìrìn-àjò kiri tí wọ́n sì nwãsù nípa àwọn ohun tí wọn ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí pẹ̀lú, tí wọ́n sì ńṣe ìrìbọmi ní orúkọ Jésù, ó sì ṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn kó ara wọn jọ tí wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kan nínú ìgbóná àdúrà àti ãwẹ̀. Jésù sì tún fi ara rẹ̀ hàn sí wọn, nítorítí wọn ngbàdúrà sí Bàbá ní orúkọ rẹ̀; Jésù sì wá, ó sì dúró lãrín wọn, ó sì wí fún wọn pé: Kíni ẹ̀yin nfẹ́ kí èmi ó fi fún yín? Wọ́n sì wí fún un pé: Olúwa, àwa fẹ́ kí ìwọ ó sọ fún wa orúkọ tí àwa ó pe ìjọ yìi; nítorípé àríyànjiyàn wà lãrín àwọn ènìyàn yĩ nípa ọ̀rọ̀ yĩ. Olúwa sì wí fún wọn pé: Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, kíni ìdí rẹ̀ tí àwọn ènìyàn yĩ fi nráhùn tí wọ́n sì njiyàn nítorí ohun yĩ? Njẹ́ wọn kòha ka ìwé-mímọ́, èyítí ó ní kí ẹ̀yin ó gba orúkọ Krístì, èyítí íṣe orúkọ mi? Nítorípé orúkọ yĩ ni a ó máa pè yín ní ọjọ́-ìkẹhìn; Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì gba orúkọ mi, tí ó sì forítì dé òpin, ohun kannã ni a ó gbàlà ní ọjọ́-ìkẹhìn. Nítorínã, ohunkóhun tí ẹ̀yin ó bá ṣe, kí ẹ̀yin ó ṣeé ní orúkọ mi; nítorínã ni ẹ̀yin ó pe ìjọ nã ní orúkọ mi; ẹ̀yin ó sì ké pe Bàbá ní orúkọ mi, kí ó lè súre fún ìjọ nã nítorí mi. Báwo ni yíò sì ṣe jẹ́ ìjọ mi bí a kò bá pẽ ní orúkọ mi? Nítorípé bí a bá pe ìjọ kan ní orúkọ Mósè, ìjọ Mósè ni íṣe nígbànã; tàbí bí a bá pẽ ní orúkọ ẹnìkan, ìjọ ẹnìkan ni íṣe nígbànã; ṣùgbọ́n bí a bá pẽ ní orúkọ mi, ìjọ mi ni íṣe nígbànã, bí ó bá jẹ́ wípé orí ìhìn-rere mi ni a kọ́ wọn lé. Lóotọ́ ni mo wí fún yín, pé orí ìhìn-rere mi ni a kọ́ yín lé; nítorínã ni ẹ̀yin ó fún ohunkóhun tí ẹ̀yin yíò fún ní orúkọ, ní orúkọ mi; nítorínã bí ẹ̀yin bá ké pe Bàbá, fún ìjọ nã, bí o bá ṣe ní orúkọ mi, Bàbá yíò gbọ́ yín; Bí ó bá sì jẹ́ wípé a kọ́ ìjọ nã lé orí ìhìn-rere mi, nígbànã ni Bàbá yíò fi àwọn iṣẹ́ ara rẹ̀ hàn nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí a kò bá kọ́ ọ lé orí ìhìn-rere mi, tí a sì kọ́ọ lé orí iṣẹ́ ènìyàn, tàbí lé orí iṣẹ́ èṣù, lóotọ́ ni mo wí fún yín, wọn ó ní ayọ̀ nínú iṣẹ́ wọn fún ìgbà díẹ̀, láìpẹ́ ọjọ́ ni òpin yíò dé, tí a ó ké wọn lulẹ̀ kí a sì sọ wọ́n sínú iná, láti inú èyítí kò sí ìpadàbọ̀. Nítorípé iṣẹ́ wọn ntọ̀ wọ́n lẹ́hìn, nítorítí a ó ké wọn lulẹ̀ nítorí iṣẹ́ wọn; nítorínã kí ẹ̀yin ó rántí àwọn ohun tí èmi ti sọ fún yín. Ẹ kíyèsĩ èmi ti fi ìhìn-rere mi fún yín, èyí sì ni ìhìn-rere èyítí èmi ti fi fún yín—pé mo wá sínú ayé láti ṣe ìfẹ́ Bàbá mi, nítorípé Bàbá mi ni ó rán mi. Bàbá mi sì rán mi kí a lè gbé mi sókè sí órí àgbélèbú; lẹ́hìn tí a sì ti gbé mi sókè sí órí àgbélèbú, kí èmi ó lè fà gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, pé gẹ́gẹ́bí ènìyàn ti gbé mi sókè bẹ̃ nã ni Bàbá yíò gbé ènìyàn sókè, láti dúró níwájú mi, láti gba ìdájọ́ iṣẹ́ wọn, bóyá rere ni wọ́n, tàbí bóyá búburú ni wọn— Àti nítọrínã ni a fi gbé mi sókè; nítorínã nípa agbara Bàbá ni èmi yíò fá gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí a lè dá wọn lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ wọn. Yíò sì ṣe, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà tí a sì se ìrìbọmi fun ní orúkọ mi, òun ni yíò kún fún Ẹ̀mí Mímọ́; bí ó bá sì forítì dé òpin, ẹ kíyèsĩ, òun ni èmi yíò kà kún aláìjẹ̀bi níwájú Bàbá mi ní ọjọ́ nã nígbàtí èmi yíò dúró ní ìdájọ́ lórí ayé. Ẹnití kò bá sì forítì dé òpin òun kannã ni ẹnití a ó ké lulẹ̀ pẹ̀lú, àti tí a ó sọ ọ́ sínú iná, nínú ibití wọn kò lè padà bọ́ mọ́, nítorí àìṣègbè Bàbá. Èyí sì ni ọ̀rọ̀ nã tí ó ti fi fún àwọn ọmọ ènìyàn. Àti nítorí ìdí yĩ ni ó fi mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ti fi fún ni ṣẹ, òun kò sì purọ́, ṣùgbọ́n ó mú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Kò sì sí ohun àìmọ́ kan tí ó lè wọ inú ìjọba rẹ̀; nítorínã ni kò sì sí ohunkóhun tí ó wọ inú ìsinmi rẹ̀ bíkòṣe àwọn tí ó ti fọ aṣọ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ mi, nítorí ìgbàgbọ́ wọn, àti ìronúpìwàdà lórí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti òtítọ́ wọn títí dé òpin. Nísisìyí èyí ni àṣẹ nã: Ẹ ronúpìwàdà, gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé, ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì ṣe ìrìbọmi ní orúkọ mi, kí ẹ̀yin ó di mímọ́ nípa gbígba Ẹ̀mí Mímọ́, kí ẹ̀yin ó lè dúró ní àìlábàwọ́n níwájú mi, ní ọjọ́ ìkẹhìn. Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, èyí ni ìhìn-rere mi; ẹ̀yin sì mọ́ àwọn ohun tí ẹ̀yin níláti ṣe nínú ìjọ mi; nítorípé àwọn iṣẹ́ tí ẹ̀yin ti rí tí èmi ṣe, òun ni kí ẹ̀yin ó máa ṣe pẹ̀lú; nítorípé ohun tí ẹ̀yin ti rí tí èmi ṣe òun pãpã ni kí ẹ̀yin ó ṣe; Nítorínã, bí ẹ̀yin bá ṣe àwọn ohun wọ̀nyí alábùkún ni ẹ̀yin íṣe, nítorípé a ó gbé yín sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn. Ẹ kọ àwọn ohun tí ẹ̀yin ti rí àti tí ẹ̀yin ti gbọ́ sílẹ̀, àfi àwọn tí a dáa yín lẹ́kun rẹ̀ ní kíkọ. Ẹ kọ àwọn iṣẹ́ àwọn ènìyàn yĩ sílẹ̀, tí yíò sì rí bẹ̃, gẹ́gẹ́bí a ti kọọ́, nípa èyítí ó ti wà tẹ́lẹ̀rí. Nítorí ẹ kíyèsĩ, láti inú àwọn ìwé tí a ti kọ, àti èyítí a ó kọ, ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn yĩ, nítorí nípa wọn ni àwọn ìṣe wọn yíò di mímọ̀ sí ènìyàn. Ẹ sì kíyèsĩ, nípasẹ̀ Bàbá ni a kọ ohun gbogbo; nítorínã láti inú àwọn ìwé tí a ó kọ ni a ó ṣe ìdájọ́ ayé. Kí ẹ̀yin kí ó sì mọ̀ pé ẹ̀yin ni onidajọ àwọn ènìyàn yĩ, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ tí èmi yíò fi fún yín, èyítí ó tọ́. Nítorínã, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ̀yin ó jẹ́? Lóotọ́ ni mo wí fún yín, àní gẹ́gẹ́ bí mo ti rí. Àti nísisìyí èmi ó lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá mi. Àti lọ́tọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin yíò bẽrè lọ́wọ́ Bàbá ní orúkọ mi, a ó fi fún yín. Nítorínã, ẹ bẽrè, ẹ ó sì rí gbà; ẹ kànkùn, a ó sì ṣíi sílẹ̀ fún yín; nítorípé ẹnìkẹ́ni tí ó bá bẽrè,yíò rí gbà; ẹnití ó bá sì kànkùn ni a ó ṣíi fún. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ayọ̀ mi pọ̀, àní tí ó kún, nítorí yín, àti ìran yĩ; bẹ̃ni, Bàbá pẹ̀lú nyọ̀, àti gbogbo àwọn ángẹ́lì mímọ́ pẹ̀lú, nítorí yín àti ìran yĩ; nítorípé kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó sọnù. Ẹ kíyèsĩ, mo fẹ́ kí ó yé yín; nítorípé àwọn tí èmi nsọ nípa wọn ni àwọn tí ó sì wà lãyé nínú ìran yĩ; kò sì sí ọ̀kan nínú wọn tí ó sọnù; nínú wọn sì ni èmi ní ẹ̀kún ayọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, mo ní ìroraọkàn nítorí ìran ẹ̀kẹ́rin sí ìran yĩ, nítorítí ó mú wọn ní ìgbèkùn, àní gẹ́gẹ́bí ó ti mú ọmọ-ègbé nnì; nítorítí wọn yíò tà mí nítorí fàdákà àti wúrà, àti nítorí èyítí kòkòrò yíò bàjẹ́ àti tí àwọn olè lè wọlé kí wọn ó jalè. Ní ọjọ́ nã ni èmi ó sì bẹ̀ wọ́n wò, àní ní dídá iṣẹ́ ọwọ́ wọn lé orí ara wọn. Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti parí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pé: Ẹ bá ẹnu-ọ̀nà híhá wọlé; nítorí híhá ni ẹnu-ọ̀nà nã, tọ́ró sì ni ojú-ọ̀nà nã èyítí ó lọ sí ti ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn ẹnití nríi; ṣùgbọ́n gbọ́rò ni ojú-ọ̀nà nã èyítí ó lọ sí ti ikú, púpọ̀ sì ni àwọn tí nrìn lójú ọ̀nà nã, tí òru sì dé nínú èyítí ẹnìkan kò lè ṣiṣẹ́. 28 Mẹ́sán nínú àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã fẹ́ láti ní ogún nínú ìjọba Krístì nígbàtí wọ́n bá kú, a sì pinnu rẹ̀ fún wọn—Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn mẹ́ta tí ó kù fẹ́ láti ní agbára lórí ikú kí wọn ó lè wà láyé títí Jésù yíò tún padà bọ̀, a sì fún wọn—A ṣí wọn nípò padà wọ́n sì rí àwọn ohun tí ó lòdì si òfin lati sọ, wọ́n sì nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ lãrín àwọn ènìyàn. Ní ìwọ̀n ọdún 34 sí 35 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Ó sì ṣe lẹ́hìn t í Jésù t i sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó bá àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ní ọ̀kọ̀kan, wípé: Kíni ìwọ fẹ́ kí èmi ó fún ọ, lẹ́hìn tí èmi yíò ti lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá? Gbogbo wọn ní ó sì sọ̀rọ̀, àfi àwọn mẹta, wípé: Àwa fẹ́ lẹ́hìn tí àwa ó bá ti lo ọjọ́ orí wa tán, tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa, èyítí ìwọ pè wá sí, yíò ti parí, kí àwa ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ nínú ìjọba rẹ ní kánkán. Ó s ì wí fún wọn p é : Alábùkún-fún ni ẹ̀yin íṣe nítorítí ẹ̀yin fẹ́ èyí láti ọwọ́ mi; nítorínã, lẹ́hìn tí ẹ̀yin báti pé ọmọ ọdún méjì lé ní ãdọ́rin ẹ́ ó wá sí ọ̀dọ̀ mi nínú ìjọba mi; ẹyin yíò sì rí ìsimi ní ọ̀dọ̀ mi. Nígbàtí ó sì ti bá wọn sọ̀rọ̀ tán, ó dojú kọ àwọn mẹ́ta nnì, ó sì wí fún wọn pé: Kíni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ó ṣe fún yín, lẹ́hìn tí èmi yíò ti lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá? Wọn sì kẹ́dùn nínú ọkàn wọn, nítorípé wọn kò jẹ́ sọ ohun tí wọn fẹ́ fún un. Ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ, mo mọ́ èrò ọkàn yín, ẹ̀yin sì ti fẹ́ ohun nã èyítí Jòhánnù, àyànfẹ́ mi, ẹnití ó wà pẹ̀lú mi nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi kí àwọn Jũ ó tó gbé mi sókè, fẹ́ kí èmi ó ṣe fún òun. Nítorínã, alábùkún-fún jùlọ ni ẹ̀yin íṣe, nítorípé ẹ̀yin kò ní rí ikú; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yíò wà lãyè láti lè rí gbogbo ìṣe Bàbá sí àwọn ọmọ ènìyàn, àní títí a ó fi mú ohun gbogbo ṣẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Bàbá, nígbàtí èmi yíò dé nínú ògo mi pẹ̀lú àwọn agbára ọ̀run. Ẹ̀yin kì yíò sì rí ìrora ikú; ṣùgbọ́n nígbàtí èmi yíò bá dé nínú ògo mi, a ó pa yín láradá ní ìṣẹ́jú láti inú ara kíkú sí ara àìkú; nígbànã ni ẹ̀yin o di alábùkún-fún nínú ìjọba Bàbá mi. Àti pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yíò sì rí ìrora ní àkokò tí ẹ̀yin ó wà nínú ara, bẹ̃ni ẹ̀yin kì yíò ní ìrora-ọkàn bíkòṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ aráyé; gbogbo ohun wọ̀nyí ni èmi yíò sì ṣe nítorí ohun tí ẹ̀yin bẽrè lọ́wọ́ mi, nítorípé ẹ̀yin ti fẹ́ kí ẹ̀yin ó lè mú ọkàn àwọn ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, nígbàtí ayé bá sì wà. Àti nítorí ìdí èyí, ẹ̀yin ó ní ẹ̀kún ayọ̀; ẹ̀yin ó sì joko nínú ìjọba Bàbá mi; bẹ̃ni, ayọ̀ yín yíò kún, gẹ́gẹ́bí Bàbá ti fún mi ní ẹ̀kún ayọ̀; ẹ̀yin ó sì rí gẹ́gẹ́ bí èmi ti rí, èmi sì rí gẹ́gẹ́ bí Bàbá; ọ̀kan sì ni Bàbá àti èmi jẹ́. Ẹ̀mí Mímọ́ sì njẹ́rĩ nípa Bàbá àti èmi; Bàbá sì nfi Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn ọmọ ènìyàn, nítorí mi. Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó fi ọwọ́ rẹ̀ kan olúkúlùkù wọn, àfi àwọn mẹ́ta nnì tí yíò kù lẹ́hìn, nígbànã ni ó lọ kúrò. Ẹ sì kíyèsĩ, awọn ọ̀run sí sílẹ̀, a sì gbé wọn lọ sínú ọ̀run, wọn sì ri, wọ́n sì gbọ́ àwọn ohun tí a kò lè sọ. A sì dá wọn lẹ́kun láti fọhùn; bẹ̃ni a kò fún wọn ní agbára láti lè sọ àwọn ohun tí wọn rí àti tí wọn gbọ́; Àti bóyá nínú ara ni tàbí kúrò nínú ara ni, wọn kò mọ̀; nítorítí wọ́n dàbí èyítí ó yípadà tí a yí wọn padà kúrò láti inú ipò àgọ́ ara sínú ipò ara àìkú, kí wọn ó lè rí àwọn ohun ti Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí wọ́n tún njíṣẹ́ ìránṣẹ́ ní orí ilẹ̀ ayé; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọn kò jíṣẹ́ ìránṣẹ́ nípa àwọn ohun tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọn ti rí, nítorí àṣẹ tí a fi fún wọn ní ọ̀run. Àti nísisìyí, bóyá wọ́n wà ní ipò ìdibàjẹ́ tàbí ní àìkú, láti àkokò ìyípadà-ara wọn, èmi kò mọ̀; Ṣùgbọ́n èyí ni èmi mọ̀, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ tí a ti kọ—wọn nlọ kiri lórí ilẹ̀ nã, wọ́n sì njíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún gbogbo àwọn ènìyàn nã, tí wọ́n sì nda ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ́ ìjọ onígbàgbọ́ nã, gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú ìwãsù wọn; tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi fún wọn, gbogbo àwọn tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi fun ni ó gba Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn tí kò darapọ̀ mọ́ ìjọ onígbàgbọ́ nã sì gbé wọn sọ sínú túbú. Àwọn túbú kò sì lè gbà wọ́n, nítorítí wọ́n sì ya sí méjì. Wọn sì gbé wọn sọ sínú ihò ilẹ̀; ṣùgbọ́n wọn bá ilẹ̀ nã jà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; tóbẹ̃ tí a fi kó wọn yọ kúrò nínú jíjìn ilẹ̀ nã nípa agbára rẹ̀; àti nítorínã wọn kò lè gbẹ́ ihò ilẹ̀ jìn tó tí yíò le sé wọn mọ́. Ìgbà mẹ́ta ni wọ́n sì gbé wọn sọ sínú iná ìléru tí wọn kò sì rí ìpalára. Ìgbà méjì ni wọ́n sì gbé wọn jù sínú ihò àwọn ẹranko búburú; ẹ sì kíyèsĩ wọn bá àwọn ẹranko búburú nã ṣeré bí ọmọdé ti íbá ọ̀dọ́-àgùtàn ṣeré, wọn kò sì rí ìpalára. Ó sì ṣe tí wọ́n nlọ kiri lãrín àwọn ènìyàn Nífáì báyĩ, tí wọ́n sì nwãsù ìhìn-rere Krístì fún gbogbo ènìyàn ní orí ilẹ̀ nã; a sì yí wọn padà sí Olúwa, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ ìjọ Krístì, báyĩ sìni àwọn ènìyàn ìran nnì di alábùkún-fún, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Jésù. Àti nísisìyí èmi, Mọ́mọ́nì, mú ọ̀rọ̀ mi wá sí òpin nípa àwọn ohun wọ̀nyí ná. Ẹ kíyèsĩ, èmi ti fẹ́rẹ̀ kọ orúkọ àwọn wọnnì tí kì yíò tọ́ ikú wò, ṣùgbọ́n Olúwa dá mi lẹ́kun rẹ̀; nítorínã ni èmi kò kọ wọ́n, nítorítí a ti fi wọ́n pamọ́ kúrò fún aráyé. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ èmi ti rí wọn, wọ́n sì ti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún mi. Ẹ sì kíyèsĩ, wọn yíò wà lãrín àwọn Kèfèrí, àwọn Kèfèrí kò sì ní mọ̀ wọ́n. Wọn yíò sì wà lãrín àwọn Jũ pẹ̀lú, àwọn Jũ kò sì ní mọ̀ wọ́n. Yíò sì ṣe, nígbàtí Olúwa yíò ríi pé ó tọ́ nínú ọgbọ́n rẹ̀ ni wọn yíò jíṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹ̀yà ìdílé Ísráẹ́lì tí ó ti fọ́nká, àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè àti ènìyàn, tí yíò sì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn jáde kúrò nínú wọn sí ọ̀dọ̀ Jésù, kí ìfẹ́ wọn ó lè di mímúṣẹ, àti nítorí agbára ti ìyínilọ́kàn padà èyítí íṣe ti Ọlọ́run tí ó wà nínú wọn. Wọ́n sì dàbí àwọn ángẹ́lì Ọlọ́run, bí wọn ó bá sì gbàdúrà sí Bàbá ní orúkọ Jésù, wọn lè fi ara hàn sí ẹnìkẹ́ni tí ó bá dára ní ojú wọn. Nítorínã, wọn yíò ṣe àwọn iṣẹ́ nlá èyítí ó yanilẹ́nu, kí ọ̀jọ́ nlá tí nbọ̀wá nnì nígbàtí gbogbo ènìyàn yíò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì; Bẹ̃ni ní ãrin àwọn Kèfèrí pãpã ni wọn ó ti ṣe iṣẹ́ nlá èyítí ó yanilẹ́nu, kí ọjọ́ ìdájọ́ nnì ó tó dé. Bí ẹ̀yin bá sì ní gbogbo àwọn ìwé-mímọ́ tí ó sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ìyàlẹ́nu Krístì, ẹ̀yin yíò mọ̀ pé àwọn ohun wọ̀nyí yíò ṣẹ dájúdájú, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ tí Krístì ti sọ. Ègbé sì ni fún ẹnìkẹ́ni tí yíò ṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Jésù, àti sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ó ti yàn tí ó sì rán lọ sí ãrin wọn; nítorípé ẹnití kò bá gba ọ̀rọ̀ Jésù àti ti ọ̀rọ̀ àwọn tí ó ti rán kò gbã; nítorínã, òun kò ní gbà wọ́n ní ọjọ́ ìkẹhìn; Ìbá sì sàn fún wọn bí a kò bá bí wọn. Njẹ́ ẹ̀yin ha rò pé ẹ̀yin lè sọ àìṣègbè Ọlọ́run tí a ti ṣẹ̀ sí di asán, ẹnití a tì tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ ènìyàn, pé ní ọ̀nà yĩ ni ìgbàlà yíò wá? Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, bí èmi ti sọ nípa àwọn wọnnì tí Olúwa ti yàn, bẹ̃ni, àní àwọn mẹ́ta wọnnì tí a gbé lọ sínú àwọn ọ̀run, pé èmi kò mọ̀ bóyá a wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò láti inú ara kíkú sí ara àìkú— Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, láti àkokò tí èmi ti kọ àkọsílẹ̀ yĩ, ni èmi ti wádĩ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, òun sì ti sọọ́ di mímọ̀ fún mi pé ó di dandan kí ara wọn ó yí padà, bí kò bá sì rí bẹ̃ wọn níláti tọ́ ikú wò; Nítorínã, kí wọn ó má bãtọ́ ikú wò ni a ṣe mú kí ara wọn ó yípadà, kí wọn ó má bá ní ìrora tàbí ìrora-ọkàn bíkòṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. Nísisìyí ìyípadà yĩ kò tóbi tó èyítí yíò bá wọn ní ọjọ́-ìkẹhìn; ṣùgbọ́n a mú ìyípadà nlá bá wọn, tóbẹ̃ tí Sátánì kò lè ní agbára rárá lórí wọn, tí kò lè dán wọn wò; tí a sì yà wọ́n sí mímọ́ nípa ti ara, tí wọ́n sì jẹ́ mímọ́, àti tí àwọn agbára inú ayé kò lè dí wọn lọ́nà. Èyí sì ni ipò tí wọn yíò wà títí di ọjọ́ ìdájọ́ Krístì; ní ọjọ́ nã wọn yíò rí ìyípadà nlá gbà, a ò sìgbà wọ́n sínú ìjọba Bàbá, tí wọn kò sì ní jáde kúrò níbẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yíò gbé pẹ̀lú Ọlọ́run títí ayérayé nínú òkè-ọ̀run. 29 Ìjádewá Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ohun àmì kan pé Olúwa ti bẹ̀rẹ̀ láti kó Ísráẹ́lì jọ àti láti mú àwọn májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ—Àwọn tí ó bá kọ̀ àwọn ìfihàn ọjọ́ ti ìkẹhìn rẹ̀ àti àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ ni a ó fi bú. Ní ìwọ̀n ọdún 34 sí 35 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín pé nígbàtí Olúwa yíò ríi nínú ọgbọ́n rẹ̀, láti mú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún àwọn Kèfèrí gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, nígbãnà ni ẹ̀yin ó tó mọ̀ pé májẹ̀mú tí Bàbá ti dá pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísráẹ́lì, nípa ìmúpadà wọn sínú ilẹ̀ ìní wọn, ti bẹ̀rẹ̀sí di ìmúṣẹ. Ẹ̀yin yíò sì lè mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa, èyítí àwọn wòlĩ mímọ́ ti sọ, yíò di mìmúṣẹ; kí ẹ̀yin ó má sì ṣe sọ wípé Olúwa yíò fa àbọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì sẹ́hìn. Kí ẹ̀yin ó má sì ròo ní ọkàn yín pé àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ jẹ́ asán, nítorí ẹ kíyèsĩ, Olúwa yíò rántí májẹ̀mú rẹ̀ èyítí ó ti bá àwọn ènìyàn rẹ̀ ti ìdílé Ísráẹ́lì dá. Nígbàtí ẹ̀yin ó bá sì ríi tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí njáde wá lãrín yín, nígbànã ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ kẹ́gàn àwọn ohun tí Olúwa nṣe mọ́, nítorí àìṣègbè idà rẹ mbẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ẹ sì kíyèsĩ, ní ọjọ́ nã, bí ẹ̀yin ó bá kẹ́gàn àwọn ohun tí Olúwa nṣe, òun yíò mú kí idà òtítọ́ rẹ̀ ó ré lù yín ní àìpẹ́. Ègbé ni fún ẹni nã tí ó nkẹ́gàn àwọn ohun tí Olúwa nṣe; bẹ̃ni, ègbé ni fún ẹni nã tí yíò sẹ́ Krístì àti àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀! Bẹ̃ni, ègbé ni fún ẹni nã tí yíò sẹ́ àwọn ìfihàn Olúwa, àti tí yíò sọ wípé Olúwa kò ṣiṣẹ́ rẹ̀ nípa ìfihàn mọ́, tàbí nípa ìsọtẹ́lẹ̀, tàbí nípa àwọn ẹ̀bùn, tabí nípa àwọn èdè, tàbí nípa ṣíṣe ìwòsàn, tàbí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́! Bẹ̃ni, ègbé sì ni fún ẹni nã, ní ọjọ́ nã, kí ó lè rí èrè, tí yíò wípé Jésù Krístì kì yíò ṣe iṣẹ́ ìyanu rárá; nítorítí ẹnití ó bá wí báyĩ ni yíò dàbí ọmọ-egbé nnì, ẹnití kò sí ãnú fún, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Krístì! Bẹ̃ni, kí ẹ̀yin ó má sì ṣe ìyọṣùtì sí tàbí kẹ́gàn tàbí fi àwọn Jũ ṣe ẹlẹ́yà mọ́, tàbí èyíkéyĩ nínú àwọn ìyókù ìdílé Ísráẹ́lì; nítorí ẹ kíyèsĩ, Olúwa yíò rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú wọn, yíò sì ṣe fún wọn ní ìbámu pẹ̀lú bí ó ti jẹ́ èjẹ́ pẹ̀lú wọn. Nítorínã kí ẹ̀yin ó máṣe rò pé ẹ̀yin lè pa ọwọ́ ọ̀tun Olúwa dà sí òsì, kí ó ma lè ṣe ìdájọ́ sí ti ìmúṣẹ májẹ̀mú èyítí ó ti dá pẹ̀lú ìdílé Ísráẹ́lì. 30 Àwọn Kèfèrí ọjọ́ ti ìkẹhìn ni a pàṣẹ fún pé kí wọn ó ronúpìwàdà, kí wọn ó wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, kí a sì kà wọ́n mọ́ ìdílé Ísráẹ́lì. Ní ìwọ̀n ọdún 34 sí 35 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Ẹ tẹ́tísílẹ̀, A! ẹ̀yin Kèfèrí, kí ẹ sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alãyè, èyítí ó ti pàṣẹ pé kí èmi ó wí fún yín nípa yín, nítorí, ẹ kíyèsĩ ó pàṣẹ fún mi pé kí èmi ó kọ sílẹ̀, wípé: Ẹ yí padà, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí, kúrò ní àwọn ọ̀nà búburú yín; kí ẹ sì ronúpìwàdà kúrò nínú ibi ṣíṣe yín, kúrò nínú irọ́ pípa àti ìwà ẹ̀tàn yín, àti ìwà àgbèrè yín, àti àwọn ohun ìríra tí ẹ̀yin nṣe ní ìkọ̀kọ̀, àti àwọn ìbọ̀rìṣà yín, àti àwọn ìpànìyàn yín, àti àwọn iṣẹ́ àlùfã àrékérekè yín, àti ìlara yín, àti àwọn ìjà yín, àti kúrò nínú gbogbo ìwà búburú àti iwa ìríra yín, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí a sì ṣe ìrìbọmi fun yín ní orúkọ mi, kí ẹ̀yin ó lè gba ìdáríjì fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, kí a lè kà yín mọ́ àwọn ènìyàn mi tí wọn íṣe ti ìdílé Ísráẹ́lì. Nífáì Kẹrin 1 A yi àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Lámánì lọ́kànpadà sí ọdọ Olúwa—Wọ́n ṣe àjùmọ̀ní ohun gbogbo, won ṣe iṣẹ́ ìyanu, wọn sì ṣe rere ní ilẹ̀ nã—Lẹ́hin igba ọdún, awọn ìyapa, ìwà ibi, àwọn ìjọ èké, àti inúnibíni dìde ní ãrín wọn—Lẹ́hìn ọ̣́dúnrún ọdun, àti àwọn ara Nífàí àti àwọn ara Lámánì di ènìyàn búburú—Ámmórọ́nì gbé àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ nã pamọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 35 sí 321 nínú ọjọ Olúwa wa. OSÌ ṣe tí ọdun kẹrìnlélọ́gbọ̀n kọjá lọ, àti ọdun karundínlógójì, ẹ sì kíyèsĩ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù tí da ìjọ Krístì sílẹ̀ nínú gbogbo ilẹ̀ tí ó yí wọn ka. Gbogbo àwọn ẹniti o bá sì tọ̀ wọ́n wa, tí wọn sì ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní tọ́tọ́, ní a rìbọmi ní ọrúkọ Jésù; wọ́n sì gbà Ẹ̀mí Mímọ́. O sì ṣe nínú ọdún kẹrìndínlógójì, gbogbo àwọn ènìyàn nã ní a sì yí lọ́kàn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa, ní ori ilẹ̀ nã, àti àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Lámánì, kò sì sí ìjà àti àríyàn-jiyàn kankan ní ãrín wọn, wọ́n sì nfi òdodo bá ara wọn lò. Wọn sì jùmọ̀ ní ohun gbogbo papọ̀; nítorínã kò sí olówó àti tálákà, òndè àti òmìnira, ṣùgbọ́n gbogbo wọn ni a sọ di òmìnira, àti alábãpín ẹ̀bùn ọ̀run nã. O sì ṣe ti ọdun kẹtadínlógójì nã kọjá lọ, àlafíà sì wà síbẹ̀ nínú ilẹ̀ nã. Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jesu sì ṣe àwọn iṣẹ́ nla tí ó yanilẹ́nu, tóbẹ̃ tí wọn mú àwọn aláìsàn lára dá, tí wọn sì jí òkú dìde, tí wọn sì mú kí àwọn amúkun ó rìn, tí wọn sì mu kí àwọn afọ́jú ó riran, àti kí odi ó gbọ́ràn; àti onírurú àwọn iṣẹ́ ìyanu ni wọ́n ṣe ni ãrín àwọn ọmọ ènìyàn; wọn kò sì ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan bíkòṣe ní orukọ Jésù. Bayĩ sì ni ọdun kejìdínlógójì kọjá lọ, àti ikọkandinlógójì pẹ̀lú, àti ìkọkànlelogoji, àtiìkejìlélógójì, bẹ̃ni, titi ọdun kọkàndínlãdọ́ta fi kọjá lọ, àti ọdun kọkànlélãdọta pẹ̀lú, àti ikéjìlelãdọta; bẹ̃ni, àti titi ọdun mọ́kàndínlọ́gọ́ta nã fi kọjá lọ. Olúwa sì mú wọn ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí wọn sì tún kọ́ àwọn ìlú-nlá sí àwọn ibití a tí jo wọn níná tẹ́lẹ̀. Bẹ̃ni, àní ìlú-nlá nnì Sarahẹ́múlà ní wọn mú kí a túnkọ́. Ṣugbọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá ni ó wà ti wọ́n ti rì, tí omi ti jáde sókè ní ipò wọn; nitorinã a kò lè tún wọn kọ́. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn Nífáì sì nlagbára síi, tí wọn sì npọ̀ síi lọ́pọ̀lọpọ̀, tí wọn sì di ènìyàn tí ó lẹ́wà tí ó sì wuni lọ́pọ̀lọpọ̀. Wọ́n sì gbéyàwó, wọ́n sì fa ìyàwó fún ni, a sì bùkún fún wọn gẹ́gẹ́bí òpọ̀lọpọ́ ìlérí tí Olúwa ti ṣe fún wọn. Wọn kò sì rìn ní ti ipa àwọn ìlànà àti ní ti òfin Mósè; ṣúgbọ́n wọn sì nrìn ní ti àwọn òfin ti wọn ti gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn, tí wọn sì ntẹ̀síwájú nínú ãwẹ̀ gbígbà àti adura, àti nínú ìdàpọ̀ nígbàkũgbà láti gbàdúrà àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. O sì ṣe tí kò sì sí ìjà lãrín gbogbo ènìyàn nã, ní gbogbo ilẹ̀ nã; sugbọn tí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jesu se àwọn iṣẹ́ ìyànù nla-nla lãrín wọn. O sì ṣe tí ọdun kọkànlélãdọ́rin kọjá lọ, àti ọdun kejilelãdọrin pẹ̀lú, bẹ̃ni, àti ni kúkúrú, títí tí ọdún kọkàndílọ́gọ́rin kọjá lọ; bẹ̃ni àní tí ọgọrun ọdun kọjá lọ, tí àwọn ọmọ èhìn Jesu, àwọn tí ó ti yàn, ti lọ sí párádísè Ọlọ́run, afi àwọn mẹ́ta nnì tí yíò durolẹ́hìn ní ayé; a sì yan àwọn ọmọ ẹ̀hìn miràn dípò wọn; àti pẹ̀lú púpọ̀ nínú ìran nnì ni ó ti kọjá lọ. O sì ṣe tí kò sì sí asọ̀ ní ilẹ̀ nã, nitori ifẹ Ọlọ́run èyítí o ngbé inu ọkàn àwọn ènìyàn nã. Ko sì sí ìlara, tabi ìjà, tabi ìrúkèrúdò, tàbí ìwà àgbèrè, tabi irọ pípa, tabi ìpànìyàn, tabi irúkírú ìwà ìfẹ́kúfẹ̃; dájúdájú kò sì sí irú àwọn ènìyàn tí ó láyọ̀ jù wọn lãrín gbogbo àwọn ènìyàn tí a ti ọwọ́ Ọlọ́run dá. Ko sí ọlọ́ṣà, tabi apànìyàn, bẹ̃ni kò sí ara Lámánì, tabi irúkìrú èléyàmẹ̀yà; ṣùgbọ́n wọn wà ní íṣọ̀kan, àwọn ọmọ Krístì, àti ajogún ìjọba Ọlọ́run. Báwo sì ní a tí bùkún wọn to! Nítorítí Olúwa nbùkún wọn nínú ohun gbogbo tí wọn nṣe; bẹ̃ni, àní Olúwa bùkún wọn o sì mú wọn se rere titi ọgọ́run ọdun o le mẹwa ti kọ́já lọ; àti ti ìran èkíní lẹ́hìn wíwá Krístì tí kọjá lọ, kò sì sí ìjà ní gbogbo ilẹ̀ nã. O sì ṣe tí Nífáì, ẹnití ó kọ àkọsílẹ̀ èyítí ó kẹ́hìn yĩ, (on sì ti kọ ọ́ sí òrí àwọn àwo Nífáì) kú, ọmọ rẹ Amọsì sì kọ ọ ní ipò rẹ̀; on sì kọ ọ́ sí orí àwọn àwo Nífáì pẹ̀lú. O sì kọ̀ ọ́ fun ọdun mẹrinlélọgọrín, alãfia sì wà ní ilẹ̀ nã, yàtọ̀ fún díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn nã tí wọn tí sọ̀tẹ̀ kúrò nínú ìjọ nã, tí wọ́n sì njẹ orúkọ àwọn ara Lámánì; nítorínã ni àwọn ara Lámánì sì tún bẹ̀rẹ̀sí wà nínú ilẹ̀ nã. O sì ṣe tí Amọsì kú pẹ̀lú, (o sì jẹ́ ọgọrũn ọdun ati ãdọ́rún ati mẹrin láti ìgbà ti Kristi ti wá) ọmọ rẹ̀ Amọsì sì kọ àwọnàkọsílẹ̀ ní ipò rẹ̀; òn nã sì kọ ọ́ le orí àwo Nífáì; o sì kọ ọ́ sínú iwe Nífáì pẹ̀lú, èyítí í ṣe ìwé yĩ. O sì ṣe tí igba ọdún ti kọjá lọ; ti gbogbo ìran kéjì tí kọjá lọ yàtọ̀ fún díẹ̀ nínú wọn. Àti nísisìyí í, emí, Mọ́mọ́nì, fẹ́ kí ẹ̀yin ó mọ̀ pe àwọn ènìyàn yĩ ti pọ̀ síi, tóbẹ̃ ti wọn tànká gbogbo orí ilẹ̀ nã, àti ti wọ́n ti di ọlọ́rọ lọpọ̀lọpọ̀; nitori ìlọsíwájú wọn nínú Krístì. Àti nísisìyí, nínú ọdun kọkànlérúgba yĩ ni àwọn kan bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín wọn tí wọn gbé ara wọn sókè nínú ìgbéraga, ní wíwọ̀ ẹ̀wù olowo-iyebíye, àti onírúurú ohun ẹ̀ṣọ́ dáradára, àti àwọn ohun dáradára ayé. Àti láti igbanã lọ ni wọn kò sì ṣe àjùmọ̀ní ohun gbogbo mọ́ ní ãrin wọn. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìyara-ẹnisọ́tọ̀ sí àwọn ẹgbẹ́; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí kọ́ àwọn ìjọ fun èrè jíjẹ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sẹ́ ìjọ Krístì tí í ṣe òtítọ́. O sì ṣe nígbàtí igba ọdún àti mẹ́wã ti kọjá lọ àwọn ìjọ púpọ̀ sì wà lórí ilẹ nã; bẹ̃ni, àwọn ìjọ púpọ̀, tí wọn kéde mímọ̀ Krístì nã, síbẹ̀síbẹ̀ wọn a mã sẹ́ púpọ̀ nínú ìhìn-rere rẹ̀, tó bẹ̃ ti wọn sì fi àyè gba onírúurú iwa búburú, ti wọn sì nfi ohun ti í ṣe mímọ́ fun ẹniti kò tọ́ sí nitori àìtọ́ rẹ̀. Ìjọ yĩ sì npọ̀sĩ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítori àìṣedẽdé, àti nitori agbara Sátánì ẹniti ó ti gba ọkàn wọn. Àti pẹ̀lú, ìjọ mĩràn wà èyítí ó sẹ Krístì nã; wọ́n sì nṣe inúnibíni sí ijọ Krístì tí í ṣe òtítọ́, nitori iwa-ìrẹ̀lẹ̀ wọn, àti ìgbàgbọ́ wọn nínú Krístì; wọn a sì mã fi wọ́n sẹ̀sín nitori àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ isẹ́ ìyanu tí wọn nṣe ní ãrin wọn. Nitorinã ní wọn sì nlo agbára àti àṣẹ lórí àwọn ọmọ ẹhin Jésù tí ó wà lãrín wọn, wọn sì jù wọn sínú tũbú; sùgbọ́n nípa agbara ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyítí ó wà nínú wọn, àwọn tũbú là sí méjì, wọ́n sì jáde lọ wọ́n sì nṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó tobi ní ãrin wọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àti l’áìṣírò gbogbo àwọn isẹ iyanu wọnyĩ, àwọn ènìyàn nã sé ọkàn wọn le, wọn sì nlépa láti pa wọn, àní gẹ́gẹ́bí àwọn Jũ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù ti lépa láti pa Jesu, gégẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì jù wọ́n sínú iná ìléru, wọn sì jáde wá ní aìní ìpalára. Wọn sì jù wọn sinu ihò àwọn ẹranko búburú, wọn si nbá àwọn ẹranko búburú nã ṣere bí ọmọde tí í bá ọ̀dọ́-àgùtàn ṣere; wọn sì jáde kúrò ní ãrín wọn, ní àìní ìpalára. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ènìyàn nã se ọkàn wọn le, nítorítí àwọn ọ̀pọ̀ àlùfã àti àwọn wòlĩ èké ní ó ndari wọn láti kó ìjọ púpọ̀ jọ, àti láti ṣe onìrũrú aisedede. Wọn sì lù àwọn ènìyàn Jésù; sugbọn àwọn ènìyàn Jesu kò lù wọ́n padà. Báyĩ sì ni wọn rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ àti iwa búburú, ní ọdọ̣́-dún, àní títí igba ọdún ati ọgbọ̀n fi kọjá lọ. Àti nísisìyí ó sì ṣe nínú ọdún yĩ, bẹ̃ni, nínú igba ọdun ati mọ́kànlé-lọ́gbọ̀n, ìyàpà nla wà lãrín àwọn ènìyàn nã. O si ṣe nínú ọdun yĩ tí àwọn ènìyàn tí a npè ní àwọn ara Nífáì dide, wọn si jẹ onígbàgbọ́ òtítọ́ nínú Krístì; nínú wọn sì ni àwọn tí àwọn ara Lamanì npè ni—àwọn ara Jákọ́bù, àti àwọn ara Jósẹ́fù, àti àwọn ara Sórámù. Nitorinã àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú Krístì ní tọ́tọ́, àti àwọn olùsìn Krístì ní tọ́tọ́, (tí àwọn ọmọ ẹ̀hìn Jésù mẹ̀ta nnì tí yíò dúró lẹ́hìn wa lára wọn) ní wọn pè ní àwọn ara Nífáì, àti àwọn ara Jakọbu, àti àwọn ara Jóṣépù, àti àwọn ara Sórámù. O sì ṣe tí a npè àwọn tí ó kọ ìhìn-rere nã ní àwọn ara Lámánì, àti àwọn ara Lémúẹ́lì, àti àwọn ara Iṣmaẹli; wọ́n kò sì rẹ̀hìn nínú àìgbàgbọ́, sùgbọ́n wọn a máa mọ̣́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí ìhìn-rere Krístì; wọn a sì máa kọ́ àwọn omọ wọn pé kí wọn ó máṣe gbàgbọ́, àní gẹ́gẹ́bí àwọn baba wọn ṣe rẹ̀hìn, láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Èyí sì rí bẹ̃ nítorí iwà búburú àti ìwà ìríra àwọn baba wọn, àní gẹ́gẹ́bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Wọ́n sì kọ́ wọn láti kórìra àwọn ọmọ Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́bí wọn ti kọ́ àwọn ara Lamanì láti kórìra àwọn ọmọ Nífáì láti ìbẹ́rẹ̀ wá. O sì ṣe ti igba ọdun àti ọdun mẹrinlélógójì ti kọjá lọ, báyĩ sì ni ìṣe àwọn ènìyàn nã rí. Àwọn tí ó sì burú jù nínú àwọn ènìyàn nã sì pọ̀ síi nínú agbára, wọ́n sì pọ̀ púpọ̀ tayọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Wọ́n sì ntẹ̀síwájú síbẹ̀síbẹ̀ láti kọ́ àwọn ìjọ fún ti ara wọn, tí wọ́n sì fi onírúurú àwọn ohun olówó-iyebíye ṣe wọ́n lọṣọ. Bayĩ sì ní igba ati ãdọta ọdún kọjá lọ, àti ọ̀tà lé rúgba ọdún pẹ̀lú. O sì ṣe tí àwọn tí ó burú nínú àwọn ènìyàn nã tún bẹ̀rẹ̀sí fí àwọn ìmùlẹ̀ òkùnkùn àti àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn Gádíátónì lélẹ̀. Àti pẹ̀lú, àwọn ènìyàn tí a pè ní àwọn ènìyàn Nífáì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìgbéraga nínú ọkàn wọn, nitorí ọrọ̀ wọn tí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ti wọ́n sì di aláinílarí bí àwọn arákùnrin wọn, àwọn ara Lamanì. Láti ìgbà yí lọ ni àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã sì bẹ̀rẹ̀sí kẹ́dùn fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. O sì ṣe nígbàtí ọ̣́dúnrún ọdún ti kọjá lọ, àti àwọn ènìyàn Nífáì àti àwọn ara Lámánì ti di ènìyàn búburú púpọ̀-púpọ̀ ní ìkọ̀kan. O s ì ṣe t í àwọn ọlọ́sà Gádíátónì tàn ká orí ilẹ̀ nã; kò sì sí ẹnití ó jẹ́ olódodo, àfi àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù. Wọn sì kó wura àti fàdákà jọ púpọ̀púpọ̀, tí wọn sì se ètò ìrìnnà ní orísirísi ọ̀nà. O sì ṣe lẹ́hìntí ọ̣́dúnrún ọdún ó lé ọdún marun tí kọjá lọ, (tí àwọn ènìyàn nã sì wa nínú ìwà búburú síbẹ̀síbẹ̀) tí Amọsì sì kú; àbúrò rẹ̀, Ámmárọ́nì sì nṣe àkọsílẹ̀ ní ipò rẹ̀. O sì ṣe nígbàtí ọ̣́dúnrún ó lé ogún ọdun ti kọjá lọ, Ámmárọ́nì, nipa ìmísí Ẹ̀mí Mímọ́, sì gbé àwọn àkọsílẹ̀ èyítí í ṣe mímọ́ nã pamọ́—bẹ̃ni, àní gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ tí a tí fifúnni láti ìran de iran, tí wọ́n jẹ mímọ́—àní t i t i de ọ̣́dúnrún ọdun ó lé ogun ọdún láti ìgbà tí Krístì tí wá. O sì gbé wọn pamọ́ nínú Olúwa, kí wọn ó lè tún padà wá sí ọ̀dọ̀ ìyókù ìdílé Jákọ́bù, gẹ́gẹ́bí àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìlérí Olúwa. Báyĩ sì ni àkọsílẹ̀ Ámmárọ́ni dé òpin. 1 Ámmórọ́nì fí àṣẹ fún Mọ́mọ́nì nípa àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ nã—Ogun bẹ̀rẹ̀ lãrín àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Lámánì—Àwọn ara Nífáì mẹ́ta nnì ní Olúwa mú lọ—Ìwà búburú, àìgbàgbọ́, ìṣóṣó àti ìṣàjẹ́, tàn kálẹ̀. Ní ìwọ̀n odun 321 sí 326, nínú ọjọ́ Olúwa wa. ÀTI nísisìyí èmi, Mọ́mọ́nì, kọ àkọsílẹ̀ nípa àwọn ohun tí mo ti rí àti tí mó tí gbọ́, mo sì pè é ní Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Àti ní ìwọ̀n àkókò tí Ámmárọ́nì gbé àwọn àkọsílẹ̀ nã pamọ́ sí Olúwa, ó wá sí ọ̀dọ̀ mi, (èmi sì jẹ́ ìwọ̀n bí ọmọ ọdún mẹ́wã, mo sì bẹ̀rẹ̀sí ní òye tí ó tayọ gẹ́gẹ́bí ti òye àwọn ènìyàn mi) Ámmárọ́nì sì wí fún mi pé: èmi wòye pé ọmọ tí ó nronú jìnlẹ̀ ni ìwọ í ṣe, ìwọ sì yára láti ṣe àkíyèsí; Nitorinã, nígbàtí ìwọ bá tó ọmọ odún mẹ́rìnlélógún, mo fẹ́ kí ìwọ ó rántí àwọn ohun tí ìwọ ti ṣe àkíyèsí rẹ̀ nípa àwọn ènìyàn yí; nígbàtí ìwọ bá sì tí tó ọmọ ọjọ́ orí nã, lọ sí ilẹ̀ Ántúmù, sí ibi òkè kan ti a ó pè ní Ṣímù; níbẹ̀ ní èmi sì ti gbé gbogbo àwọn ìfín mímọ́ nipa àwọn ènìyàn yí pamọ́ sí Olúwa. Sì kíyèsĩ, ìwọ yíò gbé àwọn àwo ti Nífáì sí ọ̀dọ̀ ara rẹ, àwọn èyítí ó kù ní ìwọ yíò fi sílẹ̀ ní ibití wọ́n wà; ìwọ́ yíò sì fín gbogbo ohun tí ìwọ tí ṣe àkíyèsí rẹ̀ nípa àwọn ènìyàn yí sí orí àwọn àwo ti Nífáì. Àti emí, Mọ́mọ́nì, tí i ṣe ìran Nífáì, (orukọ bàbá mi sì ni Mọ́mọ́nì) mo rántí àwọn ohun tí Ámmárọ́nì pa láṣẹ fún mi. O sì ṣe ti èmi, nígbàtí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlá, bàbá mi gbé mi lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù, àní sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Gbogbo ori ilẹ nã ti kún fún àwọn ilé, àwọn ènìyàn nã si ti pọ̀, ti wọn fẹ́rẹ̀ tó yànrín òkun. O sì ṣe nínú ọdun yĩ tí ogun bẹ́ silẹ̀ lãrín àwọn ará Nefáì, tí wọn í ṣe àpapọ̀ àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Jákọ́bù àti àwọn ara Jósẹ́fù àti àwọn ará Sórámù; ogun yĩ sì wà lãrín àwọn ara Nífáì, àti àwọn ará Lámánì àti àwọn ara Lẹ́múẹ́lì àti àwọn ara Íṣmáẹ́lì. Nísisìyí àwọn ara Lámánì àti àwọn ara Lẹ́múẹ́lì àti àwọn ara Íṣmáẹ́lì ni wọn npè ní àwọn ara Lámánì, àwọn ẹgbẹ méjẽjì ní àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Lámánì. O sì ṣe t í ogun nã bẹ́ silẹ̀ lãrín wọn ni agbègbè ãlà Sarahẹ́mulà, ní ẹ̀bá omi Sídónì. O sì ṣe tí àwọn ará Nífáì ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn jọ, àní èyítí ó jù ẹgbẹ̀rún lọna ọgbọ̀n lọ. O sì ṣe tí wọn ja àwọn ogun tí ó pọ̀ díẹ̀ nínú ọdún yĩ, nínú èyítí àwọn ará Nífáì ṣẹ́gun àwọn ará Lámánì tí wọ́n sì pa púpọ̀ nínú wọn. O sì ṣe tí àwọn ara Lámánì dáwọ́dúró nínú ète wọn, àlãfíà sì sọ̀kalẹ̀ sínú ilẹ̀ nã; àlãfíà sì wà fún ìwọ̀n bí ọdún mẹ́rin, tí kò sì sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ kankan. Sugbọn ìwà búburú tàn kálẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ nã, tó bẹ̃tí Olúwa fì mú àwọn àyànfẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ kúrò, iṣẹ́ ìyanu àti ìwòsàn sì dáwọ́dúró nítorí àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã. Kò sì sí àwọn ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Olúwa, Ẹ̀mí Mímọ́ kò sì bàlé ẹnikẹ́ni, nitori ìwà búburú àti àìgbàgbọ́ wọn. Àti emí, nígbàtí mo sì jẹ́ ọmọ ọdún márundínlogun, ti mo sì jẹ́ ẹnití ó nronú jinlẹ̀, nitorinã Olúwa bẹ̀ mí wò, mo sì tọ́ didara Jesu wò, mo sì mọ̣́. Mo sì gbìyànjú láti wãsù sí àwọn ènìyàn yĩ, ṣùgbọ́n ẹnu mi pa mọ́, a sì dá mi lẹ́kun láti wãsù sí wọn; nítorí kíyèsĩ wọn ti mọ̣́mọ̀ sọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run wọn; a sì mú àwọn àyànfẹ́ ọmọ ẹ̀hìn kúrò nínú ilẹ̀ nã, nitori àìṣedẽdé wọn. Sugbọn emí wà ní ãrín wọn, sùgbọ́n a dá mi lẹ́kun láti wãsù sí wọn, nitori ọkàn líle wọn; àti nitori ọkàn líle wọn, ilẹ̀ nã di ìfibú nítorí wọn. Àwọn ọlọ́sà Gádíátónì nnì tí wọ́n wà lãrín àwọn ara Lámanì, sì nyọ ilẹ̀ nã lẹ́nu, tóbẹ̃ tí àwọn tí ngbé ínú ilẹ̀ nã bẹ̀rẹ̀sí kó àwọn ohun ìní wọn pamọ́ sínú ílẹ̀; wọn kò sì rọ̀rùn láti kójọ, nítorítí Olúwa ti fi ilẹ̀ nã bú, wọn kò sì lè dì wọn mu, tàbí kí wọn ó tún ní wọn ní ìní. O sì ṣe tí ìṣoṣó àti ìṣàjẹ́, àti idán pípa; tí agbára ẹni ibi nnì sì njà lórí gbogbo ilẹ̀ nã, àní títí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ Ábínádì di mímúṣẹ, àti pẹ̀lú ti Sámúẹ́lì ará Lámánì. 2 Mọ́mọ́nì ṣíwájú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ara Nífáì—Itàjẹsílẹ̀ àti ìparun nlá gba gbogbo ilẹ̀ nã—Àwọn ara Nífáì pohùnréré ẹkún wọn sì kẹ́dùn pẹ̀lú ìrora ọkàn ẹni ègbé—Ọjọ́ ọ́re-ọ̀fẹ́ wọn ti kọjá—Mọ́mọ́nì gbà àwọn àwó Nífáì—Áwọn ogun tẹ̀síwájú. Ní ìwọ̀n ọdún 327 sí 350 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Osì ṣe nínú ọdún kannã tí ogun kan tún bẹ́ sílẹ̀ lãrín àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Lámánì. Àti l’áìṣírò mo kere ní ọjọ́ orí, emí tóbi ní gíga sókè; nitorinã ni àwọn ara Nífáì yàn mí pé kí èmi jẹ́ olórí wọn, tabi olori àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn. Nitorinã o sì ṣe ni ọdun kẹrindinlogun ọjọ́ ori mi ni emí jáde lọ ṣíwájú ẹgbẹ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì kan, ní ìkọlu àwọn ara Lamanì; nitorinã ọ̣́dúnrún ọdún ó lé mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ti kọjá lọ. O sì ṣe tí ọ̣́dúnrún ọdun ó lé mẹtadínlọ́gbọ̀n tí àwọn ara Lámáni wá kọlũ wá nínú ìgbóná agbara, tóbẹ̃ tí wọn dẹ́rùbà àwọn egbẹ ọmọ ọgun mi; nitorinã wọ̀n kọ̀ láti jà, wọ́n si bẹ̀rẹ̀sí fàsẹ́hìn sí àwọn orilẹ ede apá àríwá. O sì ṣe tí a dé ìlú-nlá Àngólà, tí a sì mú ilẹ̀ nã ní ìní, àwa sì ṣe ìmúrasílẹ̀ láti dabò bò ara wa lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì. O sì ṣe ti àwa fi gbogbo ipá wa mọ́ odi yika ìlú-nlá nã; sùgbọ́n, l’áìṣírò gbogbo imọdisí wa, àwọn ará Lámánì kọlũ wa wọ́n sì lé wa jáde kúrò nínú ìlú-nlá nã. Wọ́n sì lé wa jáde pẹ̀lú, kuro nínú ilẹ̀ Dáfídì. A sì kọjá lọ, a sì dé inú ilẹ̀ Jóṣúà, èyítí ó wà ní ibi agbègbè ilẹ̀ apá ìwọ oòrùn ní ẹ̀bá bèbè òkun. O sì ṣe tí a kó àwọn ènìyàn wa jọ ní kánkán, kí á le kó wọn papọ̀ ní ara kanṣoṣo. Ṣùgbọn ẹ kíyèsĩ, ilẹ̀ nã kún fún àwọn ọlọ́ṣà àti àwọn ara Lámánì; l’áìṣírò ìparun nla èyítí ó dó tì àwọn ènìyàn mi, wọn kò ronúpìwàdà kuro nínú àwọn ìwà ibi wọn; nitorinã ni ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìparun nlá tàn kálẹ̀ jákè-jádò oju gbogbo ilẹ̀ nã, ni ọ́dọ̀ àwọn ará Nífáì àti ni ọ́dọ̀ àwọn ara Lámánì pẹ̀lú; ó sì jẹ́ àṣe-parí ìṣọ̀tẹ̀ kan jákè-jádò gbogbo orí ilẹ̀ nã. Àti nísisìyí, àwọn ará Lámánì ní ọba kan, orukọ rẹ sì ni Áárọ́nì; ó sì kọlu wá pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún lọna ogoji o le mẹrin. Ẹ sì kíyèsĩ, mo dojú kọ ọ́ pẹ̀lu ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ó lé méjì. Ó sì ṣe tí mo lù ú pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi tí ó sì sá kúrò níwájú mi. Ẹ sì kíyèsĩ, gbogbo èyí ní a ṣe, ọ̣́dúnrún ọdun ó lé ọgbọ̀n sì kọjá lọ. Ó sì ṣe tí àwọn ara Nífáì bẹ̀rẹ̀sí ronúpìwàdà kúrò nínú iwa àìṣedẽdé wọn, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ráhùn gégẹ́bí wòlĩ Sámúẹ́lì tí sọtẹ́lẹ̀; nítorí ẹ kíyèsĩ ẹnikẹ́ni kò lè pa èyítí í ṣe tirẹ̀ mọ́, nitori àwọn olè, àti àwọn ọlọ́ṣà, àti àwọn apànìyàn, àti idán pípa, àti ìwà ìṣòṣó àti ìsàjẹ́ èyítí ó wà nínú ilẹ̀ nã. Báyĩ sì ni ó ṣe tí ọ̀fọ̀ àti ìpohùnréré-ẹkún wà nínú gbogbo ilẹ̀ nã nítorí àwọn ohun wọ̀nyí, àti pãpã ní ãrín àwọn ènìyàn Nífáì. O sì ṣe nígbàtí emí, Mọ́mọ́nì, rí ìpohùnréré-ẹkún àti ọ̀fọ̀ wọn àti ìrora-ọkàn wọn níwájú Olúwa, ọkàn mí bẹ̀rẹ̀sí yọ̀ nínú mi, nítorítí mo mọ́ ọ̀pọ̀-ãnú àti ìrọ́jú Olúwa, nitorinã emí ní èrò wípé òn yíò ṣãnú fún wọn kí wọn ó lè tún padà di olódodo ènìyàn. Sùgbọ́n ẹ kíyèsĩ ayọ̀ mi yĩ já sí asán, nítorítí ìrora-ọkàn wọn kò wà fún ti ìrònúpìwàdà, nitori dídára Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ìrora-ọkàn ti ẹni-ègbé ní í ṣe, nítorítí Olúwa kì yíò gba fún wọn rárá láti máa yọ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀. Wọn kò sì tọ Jésù wá pẹ̀lú ìròbìnújẹ́ àti ìrora ọkàn, ṣugbọ́n wọn fi Ọlọ́run bú, wọn sì fẹ́ láti kú. Bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọn a mã fi idà jà fún ẹ̀mí wọn. O sì ṣe tí ìrora-ọkan mi tún padà si ọdọ mi, èmi sì ríi pé ọjọ ọ́re-ọfẹ ti kọjá lọ pẹ̀lú wọn, ní ti ara àti ní ti ẹ̀mí; nítorítí mo ri ẹgbẹ̃gbẹ̀rún nínú wọn tí a ké lulẹ̀ nínú ìṣọ̀tẹ̀ ojukòjú wọn sí Ọlọ́run wọn, tí wọ́n sì ko wọn jọ bí imí sí ori ilẹ̀ nã. Bayĩ sì ni ọ̣́dúnrún ọdun o le mẹ́rìnlélógójì ti kọjá lọ. O sì ṣe ní ọ̣́dúnrún ọdun ó lé marundínlãdọ́ta tí àwọn ara Nífáì sì bẹ̀rẹ̀sí sálọ kúrò níwájú àwọn ara Lámánì nã; wọn sì lé wọn títí wọn fi wọ̀ inú ilẹ̀ Jáṣónì, kí wọn ó tó lè dá wọn dúró nínú sísá padà wọn. Àti nísisìyí, ìlú-nlá Jáṣọ́nì wà nítòsí ilẹ̀ nã níbití Ámmárọ́nì ti gbé àwọn àkọsílẹ̀ nnì pamọ́ si Olúwa, kí wọn ó má lè pa wọ́n run. Ẹ sì kíyèsĩ, mo sì ti ṣe gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Ámmárọ́nì, mo sì gbé àwọn àwo Nífáì, mo sì kọ àkọsílẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ Ámmórọ́nì. Àti lórí àwọn àwo Nífáì ni èmi kọ nípa gbogbo àwọn ìwà búburú nnì àti àwọn ohunìríra nã ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́; sùgbọ́n lórí àwọn àwo wọ̀nyí ni èmi fà sẹ́hìn ní kíkọ nípa ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, nítorí ẹ kíyèsĩ, nígbàgbogbo ni emí tí fi ojú mi rí àwọn ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra yĩ láti ìgbà tí emí ti dàgbà to láti ṣe àkíyèsí ìhùwàsí ọmọ ènìyàn. Ìbànújẹ́ sì wà fún mi nítorí ìwà búburú wọn; nítorí ọkàn mi tí kún fún ìrora nitori ìwà búburú wọn, ní gbogbo ọjọ ayé mi; bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo mọ̀ wípé a ó gbe mi sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn. Ó sì ṣe nínú ọdún yií tí wọ́n tún dọdẹ àwọn ènìyàn Nífáì tí wọ́n sì lé wọn. Ó sì ṣe tí wọ́n lé wa títí à fi dé ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá, lọ sí ilẹ̀ èyítí wọn npè ní Ṣẹ́mù. Ó sì ṣe tí a mọ́ odi sí ìlú-nlá Ṣẹ́mù, tí a sì kó àwọn ènìyàn wa jọ sínú rẹ̀ tó bí a ti lè ṣe, pé bóyá àwa lè gbà wọn lọ́wọ́ ìparun. Ó sì ṣe nínú ọ̣́dúnrún ọdun ó lé mẹ́rìndínlãdọ́ta tí wọn tún bẹ̀rẹ̀sí kọlù wá. Ó sì ṣe tí mo bá àwọn ènìyàn mi sọ̀rọ̀, tí èmi sì rọ̀ wọ́n pẹlú agbára nla, pé kí wọn ó dojúkọ àwọn ara Lámánì pẹ̀lú ìgboyà, kí wọn ó sì jà fún àwọn aya wọn, àti àwọn ọmọ wọn, àti àwọn ilé wọn, àti àwọn ibùgbé wọn. Ọ̀rọ̀ mi sì ru wọn sókè pẹ̀lú okun tí ó tayọ, tóbẹ̃ tí wọn kò sá fún àwọn ara Lámánì, ṣùgbọ́n tí wọ́n dúró pẹ̀lú ìgboyà ní ìdojúkọ wọn. O sì ṣe tí àwa fi ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n bá ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún lọ́nà ãdọ́ta jà. O sì ṣe tí àwa sì dúró níwájú wọn ní ìdúróṣinṣin tóbẹ̃ tí wọn sá kúrò níwájú wa. O sì ṣe nígbàtí wọ́n ti sá kúrò tí àwa sì lé wọn pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun wa, tí a sì tún dojúkọ wọ́n ní íjà, ti a sì lù wọ́n; bíótilẹ̀ríbẹ̃ sibẹ agbára Olúwa kò wà pẹ̀lú wa; bẹ̃ni, àwa nìkan ní a dáwà, tí Ẹmí Olúwa kò sì wà pẹ̀lú wa; nítorínã àwa sì ti di aláìlágbára bí àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì. Ọkàn mi sì kérora nítorí ipò ìyọnu tí àwọn ènìyàn mí wà yí, nitori ìwà búburú àti ìwà ìríra wọn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àwa jáde lọ ní ìdojúkọ àwọn ara Lámánì àti àwọn ọlọ́ṣa Gádíátónì, títí àwa tún fi padà gbà àwọn ilẹ̀ ìnì wa. Ọ̀ọ́dúnrún ọdun o le mọkàndínlãdọ́ta sì ti kọjá lọ. Nínú ọdun ọ̣́dúnrún ó lé ãdọta, àwa bá àwọn ara Lámánì àti àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì ṣe àdéhùn, nínú èyítí àwa mú kí wọn ó pín ilẹ̀ ìní wa. Àwọn ara Lámánì sì fún wa ní ilẹ̀ èyítí ó wà ní apá àríwá, bẹ̃ni, àní títí de ibi ọ̀nà tọ́ró èyítí ó lọ sí ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù. A si fun àwọn ara Lámánì ni gbogbo ilẹ ti o wa ni apá gũsu. 3 Mọ́mọ́nì nkígbe ìrònúpìwàdà sí àwọn ará Nífáì—Wọn ri ìṣẹ́gun nla gbà, wọ́n sì yangàn nínú agbára ara wọn—Mọ́mọ́nì kọ̀ láti darí wọn, àdúrà rẹ̀ fún wọn sì wà ní àìnígbàgbọ́—Ìwé ti Mọ́mọ́nì npè àwọn ẹ̀yà mejila ìdílé Ísraẹlì láti gbà ìhìn-rere nã gbọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 360 sí 362 nínú ọjọ́ Olúwa wa.O sì ṣe tí àwọn ará Lámánì kò tún wá bá àwọn ará Nífáì jagun títí ọdún mẹ́wã tún fi kọjá lọ. Ẹ sì kíyèsĩ, mo sì ti mú kí àwọn ènìyàn mi, àwọn ara Nífáì, kí wọn ó múrasílẹ̀ nínú ilẹ̀ wọn àti àwọn ohun ìjà wọn dè ìgbà ogun. Ó sì ṣe tí Olúwa wí fúnmi pe: kígbe sí àwọn ènìyàn yĩ—Ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí ẹ sì ṣe ìrìbọmi, kí ẹ sì padà tún ìjọ mi kọ́, á ó sì dá yin sí. Èmi sì kígbe sí àwọn ènìyàn yĩ, sùgbọ́n lásán ni; wọ́n kò sì rí i pé Olúwa ní ó dá àwọn sí, tí ó sì fún wọ́n ní ãyè fun ìrònúpìwada. Ẹ sì kíyèsĩ wọn sé ọkàn wọn le sí Olúwa Ọlọ́run wọn. O sì ṣe lẹ́hìn tí ọdún kẹwa yĩ ti kojá lọ, lápapọ̀ tí ó jẹ ọ̀tà lé lọ̣́dúnrún ọdún láti ìgbà tí Krístì ti wá, ọba àwọn ara Lámánì fí èpístélì kan ránṣẹ́ sí mi, èyítí ó sọ ọ́ di mímọ̀ fún mi pé wọn nṣe ìmúrasílẹ̀ láti tún padà wá íbá wa jagun. O sì ṣe tí emí mú kí àwọn ènìyàn mi kó ara wọn jọ nínú ilẹ̀ Ibi-Ahoro, sí inú ìlú-nlá kan tí ó wà ní ãlà, ní ẹ̀bá ọ̀nà tọ́ró nnì èyítí ó já sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù. Níbẹ̀ ni àwa si kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa sí, kí àwa ó lè dá àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lamanì dúró, kí wọn ó má lè mú èyíkéyi nínú àwọn ilẹ̀ wa; nítorínã nì àwa mọ́ odi mọ́ wọn pẹlú gbogbo àwọn ọmọ ogun wa. O sì ṣe nínú ọ̀tà lé lọ̣́dúnrún ọdún àti ọdún àkọ́kọ́ àwọn ará Lámánì sì sọ̀kalẹ̀ sínú ìlú-nlá Ibi-Ahoro láti bá wa jagun; ó sì ṣe nínú ọdún nã tí àwa sì lù wọ́n, tóbẹ̃ tí wọ́n tún padà sínú ilẹ̀ wọn. Nínú ọdún ọ̀tà lé lọ̣́dunrun àti ọdún kéjì ni wọ́n sì tún ṣọ̀kalẹ̀ wá bá wa jagun. Àwa sì tún lù wọ́n, a sì pa púpọ̀ nínú wọn, a sì kó àwọn òkú wọn jù sínú òkun. Àti nísisìyí, nítorí ohun nla yĩ ti àwọn ènìyàn mi, àwọn ará Nífáì, ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀sí yangàn nínú agbára ara wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí fí àwọn ọ̀run búra pé àwọn yíò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin wọn tí àwọn ọ̀tá wọ́n ti pa. Wọn sì fí àwọn ọ̀run búra, àti pẹ̀lú ìtẹ́ Ọlọ́run, pé àwọn yíò gòkè lọ bá áwọn ọ̀tá wọn jagun, tí wọn yíò sì ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí emí, Mọ́mọ́nì, sì kọ̀ jálẹ̀ láti àkókò yĩ lọ láti jẹ́ olùdarí àti olórí àwọn ènìyàn yĩ, nítorí ìwà búburú àti ìwà ẽrí wọn. Ẹ kíyèsĩ, emí ti síwájú wọn, l’áìṣírò ìwà búburú wọn, èmi ti síwájú wọn ní ọpọ̀lọpọ̀ ìgba lọ́ sí ogun, mo sì ti fẹ́ràn wọn, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ Ọlọ́run èyítí ngbé ínú mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; mo sì ti gbádúrà tọkàn-tọkàn sí Ọlọ́run mi ní gbogbo ọjọ nitori wọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, o jẹ áìní ìgbàgbọ́, nitori sísé tí wọ́n sé ọkàn wọn le. Ìgbà mẹta ni èmi sì ti gbà wọ́n kuro lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí wọn kò sì ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nígbàtí wọ́n sí ti búra pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun ti Olúwa wa àti Olùgbàlà Jésù Krístì ti kà léewọ̀ fún wọn, pé àwọn yíògòkè tọ̀ àwọn ọ̀tá wọn lọ ni ogun, tí wọn yíò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin wọn, ẹ kíyèsĩ ohùn Olúwa tọ̀ mí wa, tí ó wípé: Tèmi ni ẹ̀san, ẹmí yíò gbèsan; àti nítorípé àwọn ènìyàn yĩ kò ronúpìwàdà lẹ́hintí mo ti gbà wọ́n, ẹ kíyèsí i, a ó ke wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé. O sì ṣe tí èmi kọ̀ jálẹ̀ láti gòke lọ láti kọlũ àwọn ọ́tá mi; emí sì ṣe àní gẹ́gẹ́bí Olúwa ti pa á láṣẹ fun mi; emí sì dúró bí ẹlẹ́rĩ aláìniṣẹ́ láti fi àwọn ohun tí èmi rí àti tí èmi gbọ́ hàn fún aráyé, ní ìbámu pẹ̀lú ìfihàn ti Ẹ̀mí èyítí ó ti jẹ́rĩ nipa àwọn ohun tí mbọ̀wá. Nitorinã ni emí ṣe kọ̀wé sí yín, ẹyin Kèfèri, àti sí yín, ẹ̀yin ìdílé Isráẹ́lì, nígbàtí iṣẹ́ nã yíò bèrẹ̀, ti ẹ̀yin yíò ṣetán láti múrasílẹ̀ láti padà lọ sí ilẹ̀ ìní yin; Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, emí kọ̀wé sí gbogbo ìkangun ayé; bẹ̃ni, síi yin, ẹ̀yin ẹ̀yà méjìlá Isráẹ́lì, tí a ó ṣe ìdájọ́ yín gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ yín láti ọ́wọ́ àwọn mejìlá nnì tí Jésù yàn láti jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù. Emí sì kọwé sí ìyókù àwọn ènìyàn yĩ pẹ̀lú, tí a ó ṣe ìdájọ́ fún pẹ̀lú nípasẹ̀ àwọn méjìlá nnì tí Jésù yàn nínú ilẹ̀ yĩ; a o sì se ìdájọ́ fún wọn nípasẹ̀ àwọn méjìlá kejì tí Jésù yàn nínú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù. Àwọn ohun wọ̀nyí sì ni Ẹmí fi hàn sí mi; nitorinã ni èmi sì kọ̀wé sí gbogbo yín. Àti nítorínã ni emí ṣe kọ̀wé si yín, kí ẹyin ó lè mọ̀ pé gbogbo yín gbọ́dọ̀ dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì, bẹ̃ni, gbogbo ọkàn tí í ṣe ti ènìyàn ìdílé Ádámù; ẹ̀yin sì gbọ́dọ̀ dúró láti gba ìdájọ́ lórí iṣẹ́ yín, bóyá rere ni wọn í ṣe tàbí ibi; Àti pẹ̀lú pé kí ẹ̀yin ó lè gbà ìhìn-rere Jésù Krístì gbọ́, èyítí ẹ̀yin yíò ní lãrín yín; àti pẹ̀lú pé kí àwọn Jũ, àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa, ó lè ní ẹ̀rí míràn yàtọ̀ sí ẹnití wọ́n rí tí wọ́n sì gbọ́, pé Jésù, ẹ́nití wọn pa, ni Krístì kannã àti Ọlọ́run kannã. Emí sì ní ìfẹ́ láti rọ̀ gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé láti ronúpìwàdà kí ẹ sì múrasílẹ̀ láti dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì. 4 Ogun àti ìparun tẹ̀síwájú—Àwọn ènìyàn búburú nfìyàjẹ àwọn ènìyàn búburú—Ìwa búburú èyítí ó burú jùlọ gbilẹ̀ jù ti àtẹ̀hìnwá ní gbogbo Ísráẹ́lì—Nwọ́n fi àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé rúbọ sí àwọn òrìṣà—Àwọn ara Lámánì bẹ̀rẹ̀sí gbá àwọn ará Nífáì kúrò níwájú wọn. Ní ìwọ̀n ọdún 363 sí 375 nínú ọjọ Olúwa wa. Àti nísisìyí ó sì ṣe nínú ọ̀tà lé lọ̣́dúnrún ọdún àti ìkẹta tí àwọn ara Nífáì sì gòkè lọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn láti kọlũ àwọn ará Lámánì, kúrò nínú ilẹ Ibi-Ahoro. O sì ṣe tí wọn tún lé àwọn egbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì padà sí ilẹ̀ Ibi-Ahoro. Àti bí wọn sì ti wà nínú ipò ãrẹ̀ lọ́wọ́ ogun tí wọn njà, àkọ̀tun ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ara Lámánì tún kọ lù wọ́n; wọ́n sì jà ogun gbígbóná, tóbẹ̃ tí àwọn ara Lámánì gbà ìlú-nlá Ibi-Ahoro, tí wọn sì pa púpọ̀ nínú àwọn ara Nífáì, tí wọn sì kó púpọ̀ lẹ́rú. Àwọn tí ó kù sì sá, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn olùgbé inú ìlú-nlá Tíákúmì. Nísisìyí ìlú-nlá Tíákúmì wà ní àwọn ãlà ní ẹ̀bá bèbè òkun; ó sì tún súnmọ́ ìlú-nlá Ibi-Ahoro. Àti nítorípé àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun àwọn ara Nífáì kọjá lọ í kọlu àwọn ará Lámánì ní àwọn ara Lamanì ṣe bẹ̀rẹ̀sí pa wọ́n; nítorítí bí kò bá rí bẹ̃, àwọn ará Lámánì kì bá tí ní agbára lórí wọn. Ṣùgbọ́n, ẹ kíyèsĩ, ìdájọ́ Ọlọ́run yíò wà lórí ènìyàn búburú; nípasẹ̀ ènìyàn búburú sì ni a ó fì ìyà jẹ ènìyàn búburú; nítorípé àwọn ènìyàn búburú ní í máa rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè sí ìtàjẹ̀sílẹ̀. O sì ṣe tí àwọn ará Lámánì ṣe ìmúrasílẹ̀ láti kọlũ ìlu-nla Tíákúmì. O sì ṣe nínú ọ̀tà lé lọ̣́dúnrún ọdún à t i ìkẹrin àwọn ara Lamanì sì kọlu ìlú-nlá Tíákúmi, láti lè gbà ìlú-nlá Tíákúmì pẹ̀lú. O sì ṣe tí àwọn ara Nífáì lù wọ́n tí wọn sì lé wọn padà sẹ́hìn. Nígbàtí àwọn ará Nífáì sì ríi pe àwọn ti lé àwọn ara Lámánì padà wọn tún nyangàn nínú agbára ara wọn; wọ́n sì jáde lọ nínú ipá tí ara wọn, wọn sì tún gbà ìlú-nlá Ibi-Ahoro. Àti nísisìyí gbogbo ohun wọ̀nyí ní wọn tí ṣe, ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ni wọ́n sì ti pa ni apá méjẽjì, àti àwọn ara Nífáì àti àwọn ara Lamanì. O sì ṣe tí ọ̀tà lé lọ̣́dúnrún ọdún àti mẹfà ti kọjá lọ, àwọn ara Lámánì sì tún padà wá kọlũ àwọn ara Nífáì nínú ogun; sibẹ̀ àwọn ara Nífáì kò ronúpìwàdà kúrò nínú ìwà ibi èyítí wọn ti hù, ṣùgbọ́n wọ́n tẹramọ́ iwa búburú wọn títí. Ó sì ṣòro fún ahọ́n láti ṣe àpèjúwe, tàbí fún ènìyàn láti kọ ní pípé nípa bí ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìparun èyítí ó wà lãrín àwọn ènìyàn nã ti banilẹ́rù tó, àti nínú àwọn ara Nífáì àti nínú àwọn ara Lamanì, gbogbo ọkàn ni ó sì sé le, tí wọn sì nyọ̀ nínú ìtàjẹ̀sílẹ̀ títí. Kò sì sí irú ìwà búburú tí ó tó bayĩ rí ní ãrín gbogbo ìran Léhì, tàbí ní ãrín gbogbo ìdílé Ísraẹlì papã, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí irú èyítí ó wà lãrín àwọn ènìyàn yĩ. O sì ṣe tí àwọn ara Lamanì gbà ìlú-nlá Ibi-Ahoro nã, èyí sì rí bẹ nítorípé iye wọn tayọ iye àwọn ara Nífáì. Nwọn sì kọjá lọ pẹ̀lú láti kọlũ ìlú-nlá Tíákúmì, wọn sì lé àwọn tí ngbé inú ìlú nã jáde kúrò nínú rẹ̀, wọn sì kó ẹrú púpọ̀ àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, wọ́n sì pa wọ́n fún ìrúbọ sí àwọn òrìṣà wọn. O sì ṣe nínú ọ̀tà lé lọ̣́dúnrún ọdún o le méje, àwọn ara Nífáì bínú nítorípé àwọn ara Lámánì ti fi àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn rúbọ, wọn sí lọ í kọlũ àwọn ara Lámánì pẹ̀lú ìbínú tí ó pọ̀ púpọ̀, tó bẹ̃ tí wọn tún lù àwọn ara Lamanì, tí wọ́n sì lé wọn kúrò lórí awọn ilẹ̀ wọn. Àwọn ara Lamanì kò sì tun padà láti kọlũ àwọn ara Nífáì títí di ọ̀rìn lé lọ̣́dúnrún ọdún ó dín márún. Nínú ọdún yĩ sì ni wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti kọlũ àwọn ara Nífáì pẹ̀lú gbogbo agbára wọn;a kò sì lè kà wọ́n nítorípé iye wọn pọ̀ jùlọ. Láti àkókò yĩ lọ sì ni àwọn ara Nífáì kò lè gbà agbára lórí àwọn ara Lamanì, ṣùgbọ́n tí àwọn ará Lamanì bẹ̀rẹ̀sí pa wọ́n run àní gẹ́gẹ́bí ìrì níwájú oòrùn. O sì ṣe tí àwọn ara Lamanì sì sọ̀kalẹ̀ wa láti kọlũ ìlú-nlá Ibi-Ahoro; wọn sì ja ogun gbígbóná nínú ilẹ̀ Ibi-Ahoro, nínú èyítí wọ́n lù àwọn ara Nífáì. Wọ́n sì tún sá kúrò níwájú wọn, wọ́n sì dé ìlú-nlá Bóásì; níbẹ̀ ní wọ́n sì dojúkọ àwọn ara Lamanì pẹ̀lú ìgboyà títóbi, tóbẹ̃ tí àwọn ara Lamanì kò lù wọ́n títí wọ́n tún padà wá ní ìgbà kéjì. Nígbàtí wọn sì tún padà wa ní ìgbà kéjì, wọ́n lé àwọn ara Nífáì wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa; wọn sì tun fi àwọn obìnrin wọn àti àwọn ọmọ wọn rubọ sí àwọn orìṣà. O sì ṣe tí àwọn ara Nífáì tún sá kúrò níwájú wọn, tí wọn kó gbogbo àwọn olùgbé inú ìlú nã pẹ̀lú wọn, àti nínú àwọn ilu àti àwọn ìletò. Àti nísisìyí èmi, Mọ́mọ́nì, nítorítí mo wòye pé àwọn ara Lámánì ti fẹ́rẹ̀ gbà gbogbo ilẹ nã tan, nitorinã ni emi lọ sí orí òkè Ṣímù, tí mo sì gbé gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ èyíti Ámmárọ́nì tí gbé pamọ́ sí Olúwa. 5 Mọ́mọ́nì sì tún síwájú àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun àwọn ara Nífáì nínú àwọn ogun ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìparun—Ìwé ti Mọ́mọ́nì yíò jáde wá láti dá gbogbo Isráẹ́lì lóju pe Jésù ni Krístì nã—Nitori àìgbágbọ́ wọn, a ó fọ́n àwọn ara Lámánì ká, Ẹmí yíò sì dẹ́kun wì wà pẹ̀lú wọn—Wọ́n yíò gba ìhìn-rere láti ọwọ́ àwọn Kèfèrí ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Ní ìwọ̀n ọdún 375 sí 384 nínú ọjọ Olúwa wa. O sì ṣe tí emí sì nlọ lãrín àwọn ara Nífáì, tí mo sì ronúpìwàdà ní ti ìbúra èyíti mo tí ṣe pé èmi kì yíò tún ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ; tí wọ́n sì tún fún mi ní àṣẹ lórí àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun wọn, nítorítí wọn rí mi bí ẹnití ó lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ìpọ́njú wọn. Ṣugbọn ẹ kíyèsĩ, mo wà laìní ìrètí, nítorítí mo mọ̀ ìdájọ́ Olúwa èyítí nbọ̀ lórí wọn; nítorítí wọn kò ronúpìwàdà kuro nínú àwọn àìṣedẽdé wọn, sugbọn wọn nfí idà jà fún ẹ̀mí ara wọn làìképè Ẹni nnì tí ó dá wọn. O sì ṣe tí àwọn ara Lámánì wá láti kọlù wá nígbàtí àwa ti sálọ sí ìlú-nlá Jordánì; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, a lé wọn padà tí wọ̀n kò sì gbà ìlú nã ní àkókò nã. O sì ṣe tí wọn tún wá kọlù wá, àwa sì mú ilu nla nã lọ́wọ́. Àwọn ilu-nla miràn sì wà pẹ̀lú tí àwọn ara Nífáì mú lọ́wọ́, àwọn èyítí àwọn ibi gíga wọn jẹ idilọwọ́ fun wọn tí wọn kò sì lè wọ̀ inú orílẹ̀-èdè tí o wà níwájú wa, láti pa àwọn tí ngbé inú ilẹ̀ wa run. Sugbọn ó sì ṣe, ilẹ̀ èyíkéyĩ ti àwa bá tí là kọjá ti a kò kó àwọn tí ngbé inú ilẹ̀ nã wọlé, ní àwọn ara Lámánì parun, àti àwọn ìlú wọn, àti àwọn ìletò, àti àwọn ìlú-nlá ní wọ́n fi iná jó; báyĩ sì ni ọ̀rìn lé lọ̣́dúnrún ọdún ó dín kan kọjá lọ. O sì ṣe nínú ọ̀rìn lé lọ̣́dúnrún ọdún tí àwọn ara Lámánì sì tún wá kọlù wa ní ogun, àwa sì dojúkọ wọ́n pẹ̀lú ìgboyà; ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ jẹ lásán, nítorítí iye wọn pọ̀ tóbẹ̃ tí wọ́n tẹ̀ àwọn ara Nífáì ni abẹ́ ẹsẹ̀ wọn. O sì ṣe tí àwa tún sá, àwọn tí wọn sì yára jù àwọn ara Lámánì lọ sá àsálà, àwọn tí wọn kò sì yara to àwọn ara Lámánì ni wọn ké lulẹ̀ tí wọn sì pa wọ́n run. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, emí, Mọ́mọ́nì, kò ní ìfẹ́ láti fòró ẹ̀mí àwọn ọmọ ènìyàn níti sísọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ àti ìpànìyàn èyítí mo fi ojú ara mi rí; sugbọn emí, nítorítí mo mọ̀ pé àwọn ohun wọ̀nyí gbọ́dọ̀ dí mímọ̀ dájúdájú, àti pé ohun gbogbo tí ó pamọ́ níláti di fífihàn ní orí òrùlé— Àti pẹ̀lú pé ìmọ̀ nípa àwọn ohun wọ̀nyí níláti wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ìyókù àwọn ènìyàn yĩ, àti sí ọ̀dọ̀ àwọn Kéfèrí, àwọn tí Olúwa ti sọ wípé wọn yíò fọ́n àwọn ènìyàn yĩ ká àti pe àwọn ènìyàn yĩ dàbí ohun asán ní ãrín wọn—nitorinã ni emí ṣe kọ àkọsílẹ̀ ní ìkékúrú níwọ̀nba, ní àìgbọdọ̀ kọ ní ẹkunrẹrẹ nípa àwọn ohun ti emí ti ri, nitori òfín tí emí ti gbà, àti pẹ̀lú kí ẹ̀yin ó má bã ní ìrora-ọkàn púpọ̀ jù nitori iwa búburú àwọn ènìyàn yĩ. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èyí ní èmi sọ fún irú-ọmọ wọn, àti pẹ̀lú fún àwọn Kèfèrí tí ó nãní ìdílé Ísráẹ́lì, tí ó ní òye àti ìmọ̀ nípa ibití ìbùkún wọn ti wá. Nítorítí emí mọ̀ pe irú àwọn wọ̀nyí ni yíò kẹ́dùn ọkàn fún ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tí yíò bá ìdíle Isráẹ́lì; bẹ̃ni, wọn yíò kẹ́dùn ọkàn fún ìparun àwọn ènìyàn yĩ; wọn yíò kẹ́dùn ọkàn nítorípé àwọn ènìyàn yĩ kò ronúpìwàdà kí wọn ó lè di gbígbà fun Jesu. Nísisìyí àwọn ohun wọ̀nyí ni a kọ sí àwọn ìyókù ìdílé Jákọ́bù; a sì kọ wọn ní irú ọ̀nà yĩ, nítorípé Ọlọ́run mọ̀ pé ìwà búburú kò ní mú wọn jáde sí wọn; a ó sì gbé wọn pamọ́ nínú Olúwa kí wọn ó lè jáde wá ní àkókò tí ó yẹ nitirẹ̀. Eyí sì ni àṣẹ ti èmi ti gba; ẹ sì kíyèsĩ, wọn yíò jáde wa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa, nígbàtí o bá ríi nínú ọgbọ́n rẹ̀ pé ó tọ́ láti ṣe bẹ̃. Ẹ sì kíyèsĩ, wọn yíò sì tọ àwọn Jũ aláìgbàgbọ́ lọ, àti nítorí ìdí èyí ní wọn yíò lọ—kí a lè yi wọn lọ́kàn padà pé Jésù ni Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alãyè; kí Bàbá ó lè mú ète nla rẹ̀ tí í ṣe ti áyérayé ṣẹ, nípasẹ̀ Àyànfẹ́ jùlọ rẹ̀, láti mú àwọn Jũ padà sí ipò wọn, tabi gbogbo ìdílé Isráẹ́lì, sí ilẹ̀ ìní wọn, èyítí Olúwa Ọlọ́run wọn ti fifún wọn sí ti ìmúṣẹ májẹ̀mú rẹ̀; Àti pẹ̀lú kí irú ọmọ àwọn ènìyàn yĩ ó lè gba ìhìn-rere rẹ̀ gbọ́ sí i ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, èyítí yíò jáde tọ̀ wọn wá láti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí; nítorítí á ó fọ́n àwọn ènìyàn yĩ ká, wọn yíò sì di aláwọ̀ dúdú, wọn yíò sì di elẽrí àti ẹlẹgbin ènìyàn, tayọ apejuwe èyíkèyi tí a tí rí ní ãrin wa, bẹ̃ni, àní èyítí ó ti wa lãrín àwọn ara Lamanì, èyĩ sì rí bẹ̃ nítorí àìgbàgbọ́ wọn àti ìwà ìbọ̀rìṣa wọn. Nítorí ẹ kíyèsĩ, Ẹ̀mí Olúwa ti dẹ́kun jíjà pẹ̀lú àwọn baba wọn; wọn sì wà ni àìní Krístì àti Ọlọ́run nínú ayé; a sì ngba wọn kiri bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́. Nwọn jẹ onínúdídùn ènìyàn ní ìgbàkan rí, wọ́n sì ní Krístì gẹ́gẹ́bí olùṣọ́-àgùtàn wọn; bẹ̃ni, Ọlọ́run tí í ṣe Baba ní ó sì ndari wọn. Ṣugbọn nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, Sátánì ní ó ndari wọn kakiri, àní gẹgẹbi iyangbo tí di gbigba kiri níwájú afẹ́fẹ́, tabi bí ọkọ̀ omi tí di bíbì síwá-sẹ́hin nínú ìru omi, èyítí kò ní igbokun ọkọ̀, tabi ìdákọ̀ró, tabi ohunkóhun tí a ó fí tù ú; àti pẹ̀lú gẹ́gẹ́bí ó ti rí, bẹ̃ ni wọn rí. Ẹ sì kíyèsĩ, Olúwa ti fi ìbùkún wọn pamọ́, èyítí wọn iba gbà ní ilẹ nã, fún àwọn Kèfèrí tí yíò ní ilẹ̀ nã ní ìní. Ṣùgbọn ẹ kíyèsĩ, yíò sì ṣe ti a o lé wọn tí a o sì fọ́n wọn ka láti ọwọ àwọn Kèfèrí; lẹ́hìntí a bá sì ti lé wọn tí a sì ti fọn wọn ka láti ọwọ àwọn Kèfèrí, ẹ kíyèsĩ, nígbànã ni Olúwa yíò ranti májẹ̀mú nã èyítí ó da pẹ̀lu Ábráhámù àti pẹ̀lú gbogbo ìdílé Isráẹ́lì. Àti pẹ̀lú Olúwa yíò ranti àwọn àdúrà àwọn olódodo, èyítí wọ́n tí gbé sókè síi fún wọn. Àti nígbànã, A! ẹ̀yin Kèfèrí, báwo ni ẹyin yíò se lè duro níwájú agbara Ọlọ́run, àfi kí ẹ̀yin ó ronúpìwàdà kí ẹ sì yípadà kúrò nínú ọ̀nà ibi yín? Njẹ́ ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé ọwọ́ Ọlọ́run ni ẹyin wà bí? Njẹ́ ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé ó ní gbogbo agbara, àti pé ní àṣẹ nlá rẹ̀ ayé yíò di kíká pọ̀ bí ìwé tí a ká? Nitorinã, ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì rẹ̀ ara yín sílẹ̀ níwájú rẹ̀, kí òn ó má bã jáde wá ní àìṣègbè sí yín—kí ìyókù iru-ọmọ Jákọ́bù kan ó má bã kọjá lọ ní ãrín yín bí kìnìún, kí ó sì ya yín pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tí kò sì sí ẹnití yíò gbà yín là. 6 Àwọn ara Nífáì ko ara wọn jọ sínú ilẹ̀ Kùmórà fún àwọn ìjà ti ìgbẹ̀hìn—Mọ́mọ́nì gbe àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ nã pamọ́ sínú òkè Kùmórà—Àwọn ara Lamanì ní ìṣẹ́gun, wọn sì pa orílẹ̀-èdè àwọn ara Nifaí run—Ọgọ́run ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ni wọn fi idà pa. Ní ìwọ̀n ọdun 385 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí, mo parí àkọsílẹ̀ mi nípa ìparun àwọn ènìyàn mi, àwọn ara Nífáì. O sì ṣe ti a sì kọjá lọ níwájú àwọn ara Lámánì. Emí, Mọ́mọ́nì, sì kọ èpístélì kan sí ọba àwọn ara Lámánì, mo sì bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí o gbà fún wa láti kó àwọn ènìyàn wa lọ sí ilẹ̀ Kùmórà, ní ẹbà òkè kan tí a npè ní Kùmórà, ní ibẹ̀ ní àwa yíò sì lè dojúkọ wọn ní ìjà. O sì ṣe tí ọba àwọn ara Lámánì sì gbà fún mi nípa ohun ti èmi bèrè. O sì ṣe tí àwa kọjá lọ sí ilẹ̀ Kùmórà, tí a sì pàgọ́ wa yí okè Kùmórà nã ká; ó sì wà lórí ilẹ̀ èyítí ó ní omi púpọ̀, àwọn odò, àti àwọn orísun omi; níbíyĩ ni àwa sì ni ìrètí pé àwa yíò lè borí àwọn ara Lámánì nã. Nígbàtí ọ̀rìn lé lọ̣́dúnrún ọdún ó lé mẹ́rin sì ti kọjá lọ, àwa ti kó gbogbo àwọn ènìyàn wa tí ó kù jọ sínú ilẹ̀ Kùmórà. O sì ṣe nígbàtí a sì ti kó gbogbo àwọn ènìyàn wa jọ sí ọ̀kan ninu ilẹ̀ Kùmórà, ẹ kíyèsĩ, emí, Mọ́mọ́nì ti ndarúgbó; nítorítí mo sì ti mọ́ pe ìgbìyànjúikẹhin ni ó jẹ fún àwọn ènìyàn mi, tí Olúwa sì ti pa á láṣẹ fún mi láti máṣe jẹ́ ki àwọn àkọsílẹ̀ nã èyítí a ti gbé fún wa láti ọwọ́ àwọn baba wa, tí wọn sì jẹ mímọ́, kí wọn ó bọ sí ọwọ àwọn ará Lamanì, (nítorítí àwọn ara Lámánì yíò pa wọ́n run) nítorínã ni emí ṣe kọ àkọsílẹ̀ yĩ láti inú àwo Nífáì, ti mo sì gbé gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ tí a ti fifún mi fún ipamọ láti ọwọ Olúwa pamọ́ sínú òkè Kùmórà, àfi àwọn àwo díẹ̀ wọ̀nyí tí mo gbe fún ọmọ mi Mórónì. O sì ṣe tí àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, sì rĩ tí àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun àwọn ara Lamanì nbọ̀ ní ọ̀dọ̀ wọn; wọ́n sì duro de wọn nínú ìbẹ̀rù nla fún ikú, irú èyítí í kún ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn búburú. O sì ṣe tí wọ́n wá, láti dojú ìjà kọ wá, tí gbogbo ọkan sì kún fun ẹ̀rù nítorí bí iye wọn ti pọ̀ tó. O sì ṣe tí wọ́n sì kọlũ àwọn ènìyàn mi pẹ̀lú idà, àti pẹ̀lú ọrún, àti pẹ̀lú ọfà, àti pẹ̀lú ãké, àti pẹ̀lu onírúurú àwọn ohun ìjà ogun. O sì ṣe tí wọ́n ké àwọn ọmọ ogun mi lulẹ̀, bẹ̃ni, àní àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wã mí tí wọ́n wà pẹ̀lú mi, mo sì ṣubú pẹ̀lú ọgbẹ́ lãrín wọn; àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun àwọn ara Lámánì nã sì kọjá ní ara mi, tí wọn kò sì fi opin si ẹmi mi. Nígbàtí wọ́n sì ti kọjá lọ tí wọ́n sì ti ké gbogbo àwọn ènìyàn mi lulẹ̀ tan, afi àwa mẹ́rìnlélógún, (nínú èyítí ọmọ mi Mórónì wà), lẹ́hìn tí àwa sì ti bọ́ lọ́wọ́ ikú tí ó pa àwọn ènìyàn wa, a rĩ ni ọjọ keji, nígbàtí àwọn ara Lámánì ti padà sí àgọ́ wọn, láti ori òkè Kùmórà, àwọn ẹgbẹ̀rún mẹwa nínú àwọn ènìyàn mi ti wọn ké lulẹ̀, àwọn tí emí wà níwajú wọn bí olùdarí. Bákannã a s ì r í àwọn ẹgbẹ̀rún mẹwa nínú àwọn ènìyàn mi àwọn ẹ̀nítí ọmọ mi Mórónì síwájú. Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ̀rún mẹwa ènìyàn ti Gídgídónà ti ṣubù, òn pẹ̀lú sì wà ní ãrín wọn. Àti Lámà nã ni ó ṣubú pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹwa rẹ̀; àti Gílgálì nã ni ó ṣubú pẹ̀lu ẹgbẹ̀rún mẹwa rẹ̀; àti Límhà nã ni ó ṣubú pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹwa rẹ̀; àti Jénéúmì nã ni ó ṣubú pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹwa rẹ̀; àti Kumeníhà nã, àti Móróníhà nã, àti Ántíónọ́mù nã, àti Ṣíblọ́mù nã, àti Ṣẹ́mù nã, àti Jọ́ṣì nã, ní o ṣubu pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wã-mẹ́wã wọn. O sì ṣe ti àwọn mẹwa míràn ṣubú nipa idà, pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ̀rún mẹwa-mẹwa wọn; bẹ̃ni, àní gbogbo àwọn ènìyàn mi, bíkòṣe àwọn mẹ́rìnlélógún nnì tí wọ́n wà pẹ̀lú mi, àti àwọn díẹ̀ bákannã tí wọ́n sá lọ sínú àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà gũsù, àti àwọn díẹ̀ ti ó kọ̀ wá sílẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn ara Lámánì, ní ó ti subú; ti ẹran ara wọn àti àwọn egungun wọn àti ẹ̀jẹ̀ wọn sì wà ní orí ilẹ̀ ayé, nítorítí àwọn tí ó pa wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ kí wọn ó jẹrà lórí ilẹ̀, àti ki wọn ó fọ́ sí wẹ́wẹ́, kí wọn ó sì padà sínú ilẹ̀. Ọkàn mi sì gbọgbẹ́ pẹ̀lú àròkàn, nitori pipa tí a pa àwọn ènìyàn mi, èmi sì kígbe wipe: A! ẹ̀yin arẹwà ènìyàn, báwo ni ẹ̀yin ha se yísẹ̀padà kúrò nínú ọ̀na Olúwa! A! ẹyin arẹwà ènìyàn, báwo ní ẹ̀yin ha ṣe kọ̀Jésu, ẹnití ó dúró pẹ̀lú ìṣípá láti gbà yín! Ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin kò bá ti ṣe eleyĩ, ẹ̀yin kì bá tí ṣubú. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ ẹ̀yin ti ṣubú, èmi si nṣọ̀fọ̀ àdánù yín. A! ẹ̀yin arẹwà ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ẹ̀yin bàbá àti ìyá, ẹ̀yin ọkọ àti aya, ẹyin arẹwà ènìyàn, báwo ni ẹ̀yin ha ṣe ṣubú! Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹyin ti lọ, ìrora ọkàn mi kò sì lè mu yin padà wá. Ọjọ nã sì dé tán tí ara yín ti ayé yĩ yíò gbé ara ti àìkú wọ̀, àwọn ara wọ̀nyí tí wọ́n sì njẹrà nínú ìdíbàjẹ́ gbọ́dọ̀ di ara tí kò lè díbàjẹ́; nígbànã ni ẹ̀yin gbọ́dọ̀ dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì, kí a lè ṣe ìdàjọ́ yín gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ yín; bí ó bá si jẹ́ wípé olódodo ní ẹ̀yin í ṣe, nígbànã ní ẹ̀yin ó di alábùkún-fún pẹ̀lú àwọn baba yín tí wọ́n ti lọ ṣãjú yín. A! ẹyin ìbá sì ti ronúpìwàdà kí ìparun nlá yĩ ó tó dé bá yín. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti lọ, àti pe Bàbá nã, bẹ̃ni, Bàbá Ayérayé tí ọ̀rún, mọ̀ ipò tí ẹ̀yin wà; o sì nṣe sí yín gẹ́gẹ́bí àìṣègbè àti ãnú rẹ̀. 7 Mọ́mọ́nì pè àwọn ará Lámánì ti ọjọ́ ìkẹhìn láti gbà Krístì gbọ́, gbà ìhìn-rere rẹ̀, kí wọn ó sì rí ìgbàlà—Gbogbo ẹniti ó gba Bíbélì gbọ́ ni yíò gba Ìwé ti Mọ́mónì gbọ́ pẹ̀lú. Ní ìwọ̀n ọdún 385 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, emí yíò bá ìyókù àwọn ènìyàn yĩ tí a dásí sọ àwọn ohun díẹ̀, bí o bá ri bẹ̃ pe Ọlọ́run yíò fi àwọn ọ̀rọ̀ mi fún wọn, kí wọ́n ó lè mọ̀ nípà àwọn ohun àwọn baba wọn; bẹ̃ni, mo nbá yín sọ̀rọ̀, ẹyin ìyókù ìdílé Isráẹ́lì; ìwọ̀nyì sì ni ọ̀rọ̀ ti èmí sọ: Kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé ìdílé Isráẹ́lì ni ẹ̀yin í ṣe. Kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé ẹ níláti wa sí ìrònúpìwàdà, bí kò bá rí bẹ̃ ẹ kò lè rí ìgbàlà. Kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé ẹ níláti gbé ohun-ìjà ogun yín lélẹ́, kí ẹ̀yin ó má sì ní inú dídùn mọ́ sí ìtàjẹ̀sílẹ̀, kí ẹ̀yin ó má sì gbe wọn mọ, àfi bí Ọlọ́run bá pa á láṣẹ fún yin. Kí ẹyin kí ó mọ̀ pe ẹ níláti ní irú ìmọ̀ èyítí àwọn baba yín ni, kí ẹ sì ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn àìṣedẽdé yín, kí ẹ sì gba Jésù Krístì gbọ́, pé oun ni Ọmọ Ọlọ́run, àti pé a pa á láti ọwọ́ àwọn Jũ, àti nípasẹ̀ agbára Bàbá ó tún ti jínde, nípasẹ̀ èyítí o ti gba ìṣẹ́gun lórí isà-òkú; àti pẹ̀lú nínú rẹ̀ ni oró ikú di gbígbémì. Ó sì mú ajinde òkú ṣẹ, nípasẹ̀ èyítí a ó gbé ènìyàn dìde láti dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀. Ó sì ti mú ìràpadà ayé ṣẹ, nípasẹ̀ èyítí ẹnikẹ́ni tí à bá rí láìlẹ́bi ní iwájú rẹ̀ ní ojọ́ ìdájọ́, ni a ó fi fún láti gbe ni ọdọ Ọlọ́run nínú ìjọba rẹ̀, láti máa kọrin ìyìn ní àìdánudúró pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ akọrin tí ó wá lókè ọ̀run, sí Bàbá, àti sí Ọmọ, àti sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọn í ṣe Ọlọ́run kan, nínú ipò ayọ̀ èyítí kò ní òpin. Nitorinã, ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì ṣe ìrìbọmí ní orúkọ Jésù, kí ẹ sì dì ìhìn-rere Krístì mú, èyítí a ó gbe síwájú yín, kì í ṣe nínú àkọsílẹ̀ yĩ nìkan, ṣùgbọ́n nínú àkọsílẹ̀ èyítí yíò wá sí ọ̀dọ̀ àwọnKèfèrí láti ọ̀dọ̀ àwọn Jũ pẹ̀lú, àkọsílẹ̀ èyítí yíò wá láti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí sí ọ̀dọ̀ yín. Nítorí ẹ kíyèsĩ, a kọ eleyĩ kí ẹ́yin ó lè gbà èyí nnì gbọ́; bí ẹ̀yin bá sì gbà èyí nnì gbọ́ ẹ̀yin yíò gba èyí gbọ pẹ̀lú; bí ẹ̀yin bá sì gba èyí gbọ ẹyin yíò mọ́ nipa àwọn baba yin, àti àwọn iṣẹ tí ó yanilẹ́nu ti a ṣe nípa agbara Ọlọ́run lãrín wọn. Ẹ̀yin yíò sì mọ̀ pẹ̀lú pé ìyókù irú-ọmọ Jákọ́bù ni ẹ̀yin í ṣe; nitorinã ní a ṣe kà yín mọ́ àwọn ènìyàn ti májẹ̀mú àkọ́kọ́; bí o ba si ri bẹ̃ pe ẹ̀yin gbà Krístì gbọ́, tí a sì ṣe ìrìbọmí fun yín, ní àkọ́kọ́ pẹ̀lú omi, àti lẹhin eyi pẹ̀lú ina àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, ní títẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà wa, gẹ́gẹ́bí èyítí ó ti pa láṣẹ fún wa, yíò sì dara fún yín ní ọjọ ìdájọ́. Amin. 8 Àwọn ará Lámánì lépa àwọn ará Nífáì wọ́n sì pa wọ́n run—Ìwé ti Mọ́mọ́nì yíò jáde wá nípa agbára Ọlọ́run—A fi àwọn tí ó nmí ẽmí ìbínú àti ohùn asọ̀ sí iṣẹ́ Olúwa bú—Akọsílẹ̀ àwọn ara Nífáì yíò jáde wa ní ọjọ́ ìwà búburú, ìfàsẹ́hìn, àti ìṣubú-kúrò nínú òtítọ́. Ní ìwọ̀n ọdun 400 sí 421 nínú ọjọ Olúwa wa. Ẹ kíyèsĩ emí, Mórónì, parí àkọsílẹ̀ tí baba mi, Mọ́mọ́nì kọ. Ẹ kíyèsĩ, ohun diẹ̀ ni èmi ní láti kọ, tí ó jẹ́ àwọn ohun tí baba mi ti pa láṣẹ fún mi. Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn ogun nla àti èyítí ó pọ tí á jà ní Kùmórà, ẹ kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì tí wọn ti sálọ sinu ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìhà gũsù ní àwọn ara Lámánì dọdẹ, titi wọn fi pa gbogbo wọn run. Àti bàbá mi ni wọ́n pa pẹ̀lú, àní èmí nìkan ni o sì kù láti kọ nípà ìtàn ìparun àwọn ènìyàn mi, èyítí ó baninínújẹ́. Ṣugbọn kíyèsĩ, wọ́n ti lọ, emí sì ṣe èyítí baba mi pa láṣẹ fún mi. Bí wọn ó bá sì pa mi, èmi kò mọ̀. Nitorinã èmi yíò kọ, emí yíò sì gbé àwọn àkọsílẹ̀ nã pamọ́ sínú ilẹ̀; ibití èmi sì nlọ kò ja mọ́ nkan. Ẹ kíyèsĩ, baba mi ti ṣe àkọsílẹ̀ yĩ, o sì ti kọ ohun ti ó wà fun. Ẹ sì kíyèsĩ, emí yíò kọ ọ́ pẹ̀lú bí èmí bá rí àyè lórí àwọn àwo nã, ṣùgbọ́n èmi kò rí; emí kò sì ní irin àìpò tútù rárá, nítorítí ó kù èmi nìkan. A ti pa Bàbá mi nínú ogun, àti gbogbo àwọn ìbátan mí, èmi kò sì ní ọ̀rẹ́ tàbí ibití èmi lè lọ; èmi kò sì mọ̀ bí Olúwa yíò ti gbà kí èmi ó wa lãyè pẹ́ to. Ẹ kíyèsĩ, irinwó ọdún tí kọjá lọ láti ìgbà wíwá Olúwa àti Olùgbàlà wa. Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ara Lámánì ti dọdẹ àwọn ènìyàn mi, àwọn ara Nífáì, láti ìlú-nlá dé ìlú-nlá, àti láti ibìkan dé ibìkan, àní títí wọn fi pa gbogbo wọn; ìsubú wọn sì pọ̀; bẹ̃ni, títóbi àti ìyanilẹ́nu sì ni ìparun àwọn ènìyàn mi, àwọn ara Nífáì. Ẹ sì kíyèsĩ, ọwọ Olúwa ni ó ṣe é. Ẹ sì kíyèsĩ pẹ̀lú, àwọn ara Lámánì nbá ara wọn jagun; gbogbo orí ilẹ̀ nã ní ó sì kún fun ipanìyàn àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ títí; kò sì sí ẹnití ó mọ́ àkókò tí ogun nã dópin. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, èmi kò ṣọrọ̀ mọ́ nípa wọn, nítorítí kò síẹnikẹ́ni mọ́ àfi àwọn ará Lámánì àti àwọn ọlọ́ṣà tí ó wà lórí ilẹ̀ nã. Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ̀ Ọlọ́run otitọ bíkòṣe àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù, tí wọn duro nínú ilẹ̀ nã títí ìwà búburú àwọn ènìyàn nã fi pọ̀ tóbẹ̃ tí Olúwa kò jẹ́ ki wọn ó wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn nã; bí wọn bá sì wa lórí ilẹ̀ nã ẹnikẹ́ni kò mọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, Bábà mi àti emí ti rí wọn, wọn sì ti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ sí wa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà àkọsílẹ̀ yĩ, tí kò sì dá a lẹ́bi nitori àwọn àìpé tí ó wà nínú rẹ̀, ẹni nã ni yíò mọ̀ àwọn ohun tí ó ta àwọn wọ̀nyí yọ. Ẹ kíyèsĩ, emí ni Mórónì; bí ó bá sì ṣeéṣe ní, emí yíò sọ ohun gbogbo di mímọ̀ fún yín. Ẹ kíyèsĩ mo fi opin sí sísọ nípa àwọn ènìyàn yĩ. Emí ní ọmọ Mọ́mọ́nì, bàbá mi sì jẹ́ ìran Nífáì. Emí sì ni ẹni nã tí ó gbé àkọsílẹ̀ yĩ pamọ́ sí Olúwa; àwọn àwo rẹ̀ kò ní iye lórí, nitori àṣẹ Olúwa. Nítorítí o sọ ọ́ nítọ́tọ́ pé ẹnikẹni kò gbọ́dọ̀ ní wọ́n láti ní èrè; ṣùgbọ́n àwọn àkọsílẹ̀ inú rẹ̀ jẹ iyebíye; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ di mímọ̀, òun ni ẹnití Olúwa yíò bùkún. Nítorítí kò sí ẹniti ó lè ní agbara láti sọ ọ́ di mímọ̀ bíkòṣe kí Ọlọ́run fi í fún un; nítorítí Olọ́run fẹ kí a ṣeé pẹ̀lú ìfọkànsìn àti ògo rẹ̀ nìkán, tabi ní ìlépa àlãfíà àwọn ẹni ìgbànì ti Olúwa bá da májẹ̀mú, ti wọn sì ti di ìfọnká. Alabùkún sì ni fún ẹni nã tí yíò sọ ohun yĩ di mímọ̀; nítorítí a ó mũ jáde láti inú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ, gẹgẹbi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; bẹ̃ni, a ó múu jáde láti inu ilẹ̀, yíò sì tan jáde láti inú òkùnkùn, yíò sì wá sí ìmọ̀ àwọn ènìyàn nã; a ó sì ṣe é nípa agbara Ọlọ́run. Bí àbùkù bà sì wà nínú àkọsílẹ̀ nã, àṣìṣe tí ènìyan ni. Ṣugbọn ẹ kíyèsĩ, àwa kò mọ̀ àbùkù kankan; bíótilẹ̀ríbẹ̃ Ọlọ́run ni ó mọ̀ ohun gbogbo; nitorinã, ẹniti o bá dã lẹbi, jẹ ki o ṣọ́ra kí ó máṣe bọ́ sínú iparun iná ọ̀run àpãdì. Ẹniti ó bá sì wipe: Fi í hàn mí, bíkòjẹ́ bẹ̃ a ó lù ọ́—jẹ́ kí o sọ́ra kí o máṣe pàṣẹ èyiti Olúwa tí dánilẹ́kun rẹ̀. Nítorí ẹ kíyèsĩ, ẹniti ó bá kánjú ṣe ìdájọ́ ni a ó tún kánjú ṣe ìdájọ fún; nítorí gẹgẹbi iṣẹ́ rẹ̀ ni èrè rẹ̀ yíò rí; nitorinã, ẹniti ó bá lù ènìyàn ni Olúwa yíò tún lù. Ẹ kíyèsí ohun tí ìwé mímọ́ sọ—ẹnikẹni kò gbọ́dọ̀ lù ènìyàn, bẹ̃ni kò gbọ́dọ̀ dánilẹ́jọ́; nitori temi ni idájọ́, ni Olúwa wí, temi sì ni ẹ̀san pẹ̀lú, èmi yíò sì gbẹ̀san. Ẹniti ó bá sì mí èmí ìbínú àti ìjà sí iṣẹ́ Olúwa, àti sí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa tí í ṣe ìdílé Ísráẹ́lì, tí yíò sì wípé: Àwa yíò pa iṣẹ́ Olúwa run, Olúwa kò sì ní rántí májẹ̀mú rẹ̀ èyítí ó ti dá pẹ̀lú ìdílé Ísráẹ́lì—ẹni nã ni ó wà nínú ewu tí a ó ké e lulẹ̀, tí a ó sì sọ ọ́ sínú iná; Nítorítí èrò ayérayé Olúwa yíò tẹ̀ síwájú, títí gbogbo ìlérí rẹ̀ yíò fi di mímúṣẹ. Ẹ ṣe ìwádi nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah. Ẹ kíyèsĩ, èmi kò lè kọ wọn. Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ mo wí fún yín, pé àwọn ènìyàn mímọ́ nnì tí wọ́n ti kọjá lọ ṣãjú mi, tí wọnti ní ilẹ̀ yĩ ní ìní, yíò kígbe, bẹ̃ni, àní láti inú erùpẹ̀ wá ni wọn yíò kígbe pè Olúwa; bí Olúwa sì ti wà lãyè oun yíò rántí májẹ̀mú èyítí ó ti dá pẹ̀lú wọn. Ó sì mọ àdúrà wọn, pé fún ànfàní àwọn arákùnrin wọn ni. Ó sì mọ ìgbàgbọ́ wọn, nítorípé ní orúkọ rẹ̀ ní wọ́n lè ṣí àwọn òkè nlá ní ìdí; àti ni orúkọ rẹ̀ ní wọ́n lè mú kí ayé kí ó mì; àti nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní wọn mú kí àwọn tũbú wó lulẹ̀; bẹ̃ni, àní àwọn iná ìléru kò lè pa wọ́n lára, tàbí àwọn ẹranko búburú tàbí àwọn ejò olóró, nítorí agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kí ẹ sì kíyèsĩ, adura wọn wà fún ànfàní ẹnití Olúwa yíò jẹ́ kí ó mú àwọn ohun wọ̀nyí jáde wá. Kí ẹnikẹni ó má sì sọ pé wọn kò ní wá, nítorí dájúdájú wọn yíò wá, nítorípé Olúwa ti wíi; nítorítí wọn yíò jáde wá láti inú erùpẹ̀, nipa ọwọ́ Olúwa, kò sì sí ẹniti ó lè dá a dúró; yíò sì wá ní ọjọ́ nã nígbàtí wọn yíò wípé iṣẹ́ ìyanu kò sí mọ́; yíò sì wá àní bí ẹnití nsọ̀rọ̀ láti inú ipò-òkú. Yíò sì wá ní ọjọ́ nã nígbàtí ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ yíò kígbe pe Olúwa, nitori àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn àti àwọn iṣẹ ìkọ̀kọ̀. Bẹ̃ni, yíò wá ní ojọ́ nã nígbàtí àwọn ènìyàn yíò sẹ́ agbara Ọlọ́run ti àwọn ìjọ onígbàgbọ́ yíò di àìmọ́, tí wọn yíò sì gbé ara wọn sókè nínú ìgbéraga ọkan wọn; bẹ̃ni, àní ni ọjọ́ nã nígbàtí àwọn oludari àwọn ijọ onígbàgbọ́ àti àwọn olùkọ́ni yíò gbe ara wọn sókè nínú ìgbéraga ọkàn wọn, àní títí wọ́n fi jẹ́ ohun ìlara sí àwọn tí ó wà nínú àwọn ìjọ onígbàgbọ́ wọn. Bẹ̃ni, yíò wá ní ọjọ́ nã nígbàtí a ó mã gbọ́ nípa àwọn ìsẹ̀lẹ̀ iná, àti èfũfùlíle, àti ìkùukùu ẽfin láti inú àwọn ìlẹ̀ òkẽrè wá. A ó sì tún gbọ́ pẹ̀lú nípa àwọn ogun, ìdágìrì ogun, àti àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ní onírúurú ibi. Bẹ̃ni, yíò wá ní ọjọ́ nã nígbàtí àwọn ìbàjẹ́ èyítí ó pọ̀ yíò wà lórí ilẹ̀ ayé; ìpànìyàn yíò wà, àti olè jíjà, àti irọ́ pípa, àti ẹ̀tan, àti ìwà àgbèrè, àti onírúurú ìwà ìríra; nígbàtí púpọ̀ ènìyàn yíò wipe: Ṣe tibí, tabi ṣe tọ̀hún, àti pe kò já mọ́ ohun kan, nítorípé Olúwa yíò gbe irú àwọn ẹni bẹ̃ dúró ní ọjọ ìkẹhìn. Ṣugbọ́n ègbé ni fún irú àwọn ẹni bẹ̃, nítorípé wọn wà nínú ìkorò òrọ́ro àti ìdè àìṣedẽdé. Bẹ̃ni, yíò ṣe ní ọjọ́ nã nígbàtí a ó kọ́ àwọn ìjọ onígbàgbọ́ tí wọn yíò mã wípé: Wá sí ọ̀dọ̀ mi, àti fún owó rẹ, a ó dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. A! ẹ̀yin oníwà búburú àti alárèkérekè àti ọlọ́rùnlíle ènìyàn, kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin fi kọ ijọ onigbagbọ́ jọ fún ara yin láti jẹ èrè? Kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin yí ọ̀rọ̀ mímọ́ ti Ọlọ́run padà, kí ẹ̀yin ó lè mú ègbé wá sí órí ọkàn yin? Ẹ kíyèsĩ, ẹ wò inú àwọn ìfihàn Ọlọ́run; nítorí ẹ́ kíyèsĩ, àkókò dé tán ní ojọ nã nígbàtí gbogbo àwọn ohun wọnyĩ gbọdọ̀ di mímúṣẹ. Ẹ kíyèsĩ, Olúwa ti fi àwọn ohun nla tí ó yanilẹ́nu hàn mí nípa eyĩnì tí ó gbọ́dọ̀ dé ní àìpẹ́, ní ọjọ nã nígbàtí àwọn ohun wọnyĩ yíò jáde wa ní ãrín yín. Ẹ kíyèsĩ, mo nbá yín sọ̀rọ̀ bí ẹnipé ẹ̀yin wà níhìn yĩ, síbẹ̀ ẹ̀yin kò sì níhìn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ,Jésù Krístì ti fi yín hàn sí mi, èmi sì mọ́ àwọn ìṣe yín. Emí sì mọ̀ pé ẹ̀yin nrìn nínú ìgbéraga ọkàn yín; àti pe kò sì sí nínú yin, afi díẹ̀ tí kò gbé ara wọn sókè nínú ìgbéraga ọkàn wọn, sí wíwọ̀ ẹ̀wù olówó iyebíye, ṣí ṣíṣe ìlara, àti ìjà, àti àrankàn, àti inúnibíni, àti onírúurú ìwà àìṣedẽdé; tí àwọn ijọ onígbàgbọ́ yin, bẹ̃ni, àní gbogbo wọn, ní ó ti díbàjẹ́ nítorí ìgbéraga ọkàn yín. Nítorí ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin fẹ́ràn owó, àti ohun ìní yín, àti àwọn ẹ̀wù olowo iyebíye yín, àti ṣíṣe àwọn ijọ yín lọ̀ṣọ́, jù bí ẹ̀yin ti fẹ́ràn àwọn òtòsi àti àwọn aláìní, àwọn aláìsàn àti àwọn ti á pọn lójú. A! ẹyin oníbàjẹ́, ẹyin àgàbàgebè, ẹyin olùkọ́ni, tí ẹ ntà ara yín fun èyítí yíò díbàjẹ, kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin ṣe bá ìjọ mímọ́ Ọlọ́run jẹ́? Kíni ojú ṣe ntì yín láti gbà orúkọ Krístì sínú yin? Ẹyin kò ṣe rò ó pé iye tí ó wà lórí ayọ̀ àìnípẹ̀kun jù ti òṣì tí kì í kú—nítorí ìyìn ti inú ayé yi? Kíni ìdì rẹ̀ ti ẹ̀yin nṣe ara yín lọ́ṣọ pẹ̀lú èyítí kò ní ẹ̀mí, tí ẹyin sì njẹ́ kí ẹnití ebi npa, àti aláìní, àti ẹniti ó wà làìláṣọ lárá, àti alaisàn àti ẹniti a pọ́n lójú kí ó kọjá ní ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ kò sì nãní wọn? Bẹ̃ni, kíni ìdí rẹ̀ tí ẹyín nkó àwọn ohun irira yín ìkọ̀kọ̀ jọ fún èrè jíjẹ, tí ẹ sì nmú kí àwọn opó ṣọ̀fọ̀ níwájú Olúwa, àti pẹ̀lu kí àwọn ọmọ alainibaba ṣọ̀fọ̀ níwájú Olúwa, àti kí ẹ̀jẹ̀ àwọn bàbá wọn àti àwọn ọkọ wọn kígbe pe Olúwa láti inú ilẹ̀ wa, fún ìgbẹ̀san lórí yin? Ẹ kíyèsĩ, idà ìgbẹ̀san nrọ̀dẹ̀dẹ̀ lórí yín; àti pé àkókò nã fẹ́rẹ̀ dé tí oun yíò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ lórí yín, nítorítí oun kì yíò jẹ́ kí wọn ó ké mọ. 9 Mórónì pè àwọn tí kò gbà Krístì gbọ́ láti ronúpìwàdà—O kéde Ọlọ́run oníṣẹ́ ìyanu, tí í fúnni ní ìfihàn àti tí í dà àwọn ẹ̀bùn àti àmì le ori àwọn olótĩtọ́—Iṣẹ ìyanu dáwọ́ dúró nitori àìgbàgbọ́—Àwọn àmì a máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ—A rọ̀ àwọn ènìyàn láti jẹ ọlọgbọ́n kí wọn ó sì pa àwọn òfin mọ. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí, emí sọ̀rọ̀ pẹlu nípa àwọn ẹniti kò gbà Krístì gbọ́. Ẹ kíyèsĩ, njẹ ẹ̀yin ó ha gbàgbọ́ ni ọjọ ìbẹ̀wò yin—Ẹ kíyèsĩ, nígbàtí Olúwa yíò wa, bẹ̃ni, àní ní ọjọ́ nlá nã nígbàtí ayé yíò di kíká pọ̀ bí ìwé, tí àwọn ẹ̀yà inú rẹ̀ yíò yọ́ nínú ìgbóná ọ́ru, bẹ̃ni, ní ọjọ nla nã nígbàtí a ó mú yín dúró níwájú Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run—nigbànã ni ẹ̀yin ó ha wípé Ọlọ́run kò sí bi? Nígbànã ni ẹ̀yin ó ha tún sẹ́ Krístì nã síi bí, tábi njẹ ẹ̀yin lè fí ojú rí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run nã bi? Njẹ́ ẹyin ha rò wípé ẹ ó bã gbé pọ̀ nínú ìmọ̀ ìdálẹ́bi yín bí? Njẹ́ ẹ̀yin ha rò wípé ẹyin lè ní inú dídùn láti bá Ẹni mímọ́ nnì gbé pọ̀ bi, nígbàtí ìmọ̀ ìdálẹ́bi ngbo ọkàn yin pé gbogbo ìgbá ní ẹ̀yin a mã rú òfin rẹ́ bí? Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín pé ẹ̀yin yíò wà ní ipò òtòsì bí ẹ́bá ngbé pọ pẹ̀lú Ọlọ́run mímọ́ olódodo, nínú ìmọ̀ ìwà ọ̀bùn yin níwájú rẹ̀, jú kí ẹyin ó bá àwọn ọkàn tí ó ti ṣègbé gbé pọ̀ nínú ọ̀run àpãdì. Nitori ẹ kíyèsĩ, nígbàtí á ó bá mú yín láti lè rí ìhòhò yín níwájú Ọlọ́run, àti pẹ̀lú ogo Ọlọ́run, àti mímọ́ Jésù Krístì, yíò tàn ìna tí a kò lè pa lè yín lórí. A! bí ó bá rí bẹ̃ ẹ̀yin aláìgbàgbọ́, ẹ yípadà sí ọ̀dọ̀ Olúwa; ẹ́ kígbe kíkan-kíkan pè Baba ní orúkọ Jésù, pe bóyá a ó rí yín ni ipò àìlábàwọ́n, ní mímọ́, ní rirẹwà, àti ní funfun, lẹhinti a ti fi ẹjẹ Ọ̀dọ́-àgùtàn wẹ̀ yín mọ́, ní ọjọ nla tí ó kẹ́hìn. Àti pẹ̀lú mo bá yin sọ̀rọ̀ ẹ̀yin tí ó nsẹ́ àwọn ìfihàn ti Ọlọ́run, tí o wípé a tí dáwọ́ wọn dúró, pé kò sí àwọn ìfihàn mọ, tabi àwọn i sọtẹlẹ, tabi àwọn ẹbun, tabi ìwòsàn, tabi fifi onírúrú èdè fọ̀, àti ìtumọ̀ onírúrú èdè; Ẹ kíyèsĩ mo wí fún yín, ẹniti ó bá sẹ́ àwọn ohun wọ̀nyí kò mọ̀ ìhìn-rere Krístì; bẹ̃ni, kò tí ì kà àwọn ìwé-mímọ́; bí ó bá sì ti kà wọ́n, wọn kò yé e. Nitori njẹ àwa kò ha rí i kà pé Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kannã ní àná, ní òní, àti títí láé, àti nínú rẹ̀ ni kò sì sí ìyípadà tàbí òjìji àyídà? Àti nísisìyí, bí ẹ̀yin bá ti rò nínú ọkàn yín nípa òrìṣà nã tí í máa yípadà àti nínú ẹnití òjiji àyípadà wà, nígbànã ni ẹ̀yin ti rò nínú ọkan yín nípa òrìṣa tí kì í ṣe Ọlọ́run oníṣẹ́ ìyanu. Ṣugbọn ẹ kíyèsĩ, èmi yíò fi Ọlọ́run oníṣẹ́ ìyanu hàn yín, àní Olọ́run Ábráhámù, àti Ọlọ́run Ísãkì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù; àti pé Ọlọ́run nnì oun kannã ni ó dá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn. Ẹ kíyèsĩ, ó da Ádámù, àti pe nípasẹ̀ Ádámù ní ìṣubú ènìyàn fi wá. Nítorí ìṣubú ènìyàn sì ni Jésù Krístì fi wá, àní Bàbá àti Ọmọ; nítorí Jésù Krístì sì ni ìràpadà ènìyàn fi wá. Àti nitori ìràpadà ènìyàn, èyítí ó wá nípasẹ̀ Jésù Krístì, amú wọn padà wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa; bẹ̃ni, nípa èyí ní a ra gbogbo ènìyàn padà, nítorípé ikú Krístì mú àjíndé wá sí ìmúṣẹ, èyítí ó sì mú ìràpadà kuro nínú ọ́run àìnípẹ̀kun wa sí ìmúṣe, nínú ọ́run èyíti gbogbo ènìyàn yíò jínde nípa agbara Ọlọ́run nígbàtí ìpè nã yíò dún; wọn yíò sì jáde wa, àti èyítí ó kere àti èyítí ó tóbi, gbogbo wọn ní yíò sì dúró ní iwájú ìdájọ́ rẹ̀, nítorípé á ti rà á padà a sì ti túu sílẹ̀ kuro nínú ìdè ikú ayérayé, ikú èyítí í ṣe ikú ti ara. Nígbànã sì ni ìdájọ́ Ẹní Mímọ́ nnì yíò dé bá wọn; nigbanã sì ni àkókò nã yíò de tí ẹnití ó bá jẹ elẽrí yìò wá ní ipò èlẽrí síbẹ̀; ẹnití ó bá sì jẹ olódodo yíò wa ní ipò olododo síbẹ; ẹniti ó bá ní inúdídùn yíò wa ní ipò inúdídùn síbẹ̀; ẹniti o bá sì wa láìní inúdídùn yíò wa ní ipò aláìní inúdídùn síbẹ̀. Àti nísisìyí, A! gbogbo ẹ̀yin ti ẹ́ ti rò nínú ọkàn yín nípa òrìṣà nã èyítí kò lè ṣe iṣẹ́ ìyánú, emí yíò bí yín lẽrè, njẹ́ àwọn ohun wọ̀nyí ti rékọjá bí, àwọn ohun ti emí ti sọ nipa wọn? Njẹ òpin ti de bi? Ẹ kíyèsĩ mo wi fún yín, Rárá; Ọlọ́run kò sì dẹ́kun láti jẹ Ọlọ́run oníṣẹ́ ìyanu. Ẹ kíyèsĩ, njẹ àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe kò ha jẹ́ ìyanu níojú wa bí? Bẹ̃ni, tani ó sì lè mọ̀ àwọn iṣe Ọlọ́run tí ó yanilẹ́nu? Tani yíò wípé kì í ṣe iṣẹ́ ìyanu pé nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀ ọrun àti aiyé ní lati wà; àti nipa agbara ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a da ènìyàn láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀; àti nipa agbara ọrọ rẹ̀ ni a ṣe àwọn iṣẹ iyanu? Àti pé tani yíò wípé Jésù Krístì kò ṣe ọpọlọpọ iṣẹ ìyanu nla? Àwọn iṣẹ iyanu nla púpọ̀púpọ̀ sì ni a t i ọwọ́ àwọn àpóstélì ṣe. Bí wọ́n bá sì ṣe àwọn iṣẹ ìyanu ní ìgbà nã, kini idi rẹ̀ tí Ọlọ́run fi dẹ́kun láti jẹ Ọlọ́run onisẹ ìyanu àti síbẹ̀síbẹ̀ tí í sì í ṣe Ẹda tí a kò lè yípadà? Ẹ sì kíyèsĩ, mo wí fun yín kĩ yípadà; bí ó bá rí bẹ̃ oun yíò dẹ́kun láti jẹ Ọlọ́run; oun kò sì dẹ́kun láti jẹ Ọlọ́run, ó sì jẹ́ Ọlọ́run oníṣẹ́ ìyanu. Ìdí rẹ tí òun fi dẹ́kun láti ṣe iṣẹ́ ìyanu ní ãrín àwọn ọmọ ènìyàn ní nítorípé wọ́n rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì yẹ̀ kúrò nínú ọnà èyíti ó tọ́, wọn kò si mọ̀ Ọlọ́run nínú ẹnití ó yẹ kí wọn ó gbẹ́kẹ̀lé. Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín pe ẹnikẹni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Krístì, ní aisiyemeji rara, ohunkóhun tí ó bá bèrè lọ́wọ́ Bàbá ní orukọ Krístì a o fi fún un; ìlérí yĩ sì wà fún gbogbo ènìyàn, àní títí de ìkangun ayé. Nítori ẹ kíyèsĩ, báyĩ ni Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run wí fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ àwọn ẹnití yíò dúró lẹ́hìn, bẹ̃ni, àti fún gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀, tí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sì gbọ́ ọ pe: Ẹ lọ sínú gbogbo ayé, kí ẹ sì wãsù ìhìn-rere nã sí gbogbo ẹ̀dá; Ẹniti ó bá sì gbàgbọ́, tí a sì rìbọmi ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n ẹnití kò bá gbàgbọ́ ní a ó dálẹ́bi; Àwọn àmì wọ̀nyí sì ni yíò máa tẹ̀lé àwọn tí ó gbàgbọ́—ní orúkọ mi ni wọn yíò lé àwọn èṣù jáde; wọn yíò fí èdè titun sọ̀rọ̀; wọn yíò mú àwọn ejò soke; tí wọn bà sì mu ohunkóhun tí ó ní oró kì yíò pa wọ́n lára; wọn yíò gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn a sì dà; Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà orúkọ mi gbọ́, tí kò siyèméjì rárá, sí ẹni bẹ̃ ni emí yíò fi idi gbogbo ọrọ mi mulẹ̀, àní titi dé ìkangun ayé. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, tani ó há lè dojúkọ iṣẹ́ Olúwa? Tani ó ha lè sẹ́ àwọn ohun tí ó sọ? Tani yíò ha dide sí agbara Olúwa títóbi julọ? Tani yíò ha kẹ́gàn iṣẹ́ Olúwa? Tani yíò ha kẹ́gàn àwọn ọmọ Krístì? Ẹ kíyèsĩ, gbogbo ẹyin tí í fi iṣẹ́ Olúwa ṣẹ̀sín, nitori ẹnú yíò ya yín ẹ ó sì parun. A! nigbanã kí ẹ má sì ṣe kẹgan, ki ẹnu ó ma sì yà yín, sugbọn ẹ tẹ́tísí ọrọ Olúwa, kí ẹ sì bẽrè lọ́wọ́ Bàbá ni orúkọ Jésù fun ohunkóhun tí ẹ̀yin ṣe aláìní. Ẹ máṣe ṣiyemejì, ṣùgbọ́n kí ẹ gbàgbọ́, kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ gẹgẹbí ìgbà àtijọ́, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkan yín, kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ ìgbàlà yin pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì níwájú rẹ̀. Ẹ jẹ ọlọgbọ́n ní ọjọ ìdánwò yín; ẹ mú gbogbo ìwà àìmọ́ kuro nínú yín; ẹ máṣe bẽrè fun ohun kan láti lè lò ó fun ìfẹ́kúfẹ ara yín, ṣùgbọ́n kí ẹ bẽrè pẹ̀lú ìdúró-ṣinṣin láì siyèméjì, pé kí ẹ máṣe gbà àdánwò lãyè, ṣùgbọ́n pé ẹ̀yín yíò máa sìn Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè. Kí ẹ rí i pe ẹ̀yin kò ṣe ìrìbọmi ní àìpé; kí ẹ ríi pé ẹyin ko jẹ nínú àmì májẹ̀mú ní àìpé; ṣùgbọ́n kí ẹ rí i pe ẹyin ṣe ohun gbogbo ni pípé, kí ẹ sì ṣe é ní orukọ Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alãyè; bí ẹyin bá sì ṣe èyí, ti ẹ sì forítì í de òpin, a kì yíò ta yín nù. Ẹ kíyèsĩ, mo nbá yín sọrọ bí ẹnipé láti ipo-oku ní emí ti nsọ̀rọ̀; nítorípé mo mọ̀ pé ẹyin yíò gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Ẹ máṣe dá mi lẹ́bi nítori àwọn àbùkù mi, tabi baba mi, nitori àwọn àbùkù rẹ̀, tabi àwọn tí ó ti kọ̀wé ṣãjú rẹ̀; sugbọn kí ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run pé o ti fi àwọn àbùkù wa hàn sí yín, kí ẹyin ó lè kọ́ láti jẹ́ ọlọgbọ́n jù bí àwa tí jẹ́. Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, awá ti kọ àkọsílẹ̀ yĩ gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú bí àwa ti í kọ̀wé ní ãrin wa èyítí a npè ni àtúnṣe èdè Égíptì, èyítí a gbé lé wa lọ́wọ́ láti ìran kan dé òmíran tí a sì yípadà, ni ìbámu pẹ̀lú èdè wa. Bí ó bá sì ṣe pe àwọn àwo wa tóbi tó ni àwa ìbá ti kọ ìwe yìi ni èdè Hébérù; ṣùgbọ́n a ti yí ede Hébérù nã padà pẹ̀lú; bí ó bá sì ṣe pé àwa lè kọ̀wé ní ede Hébérù, kíyèsĩ, ẹ̀yin kì bá tí rí àìpé kankan nínú àkọsílẹ̀ wa. Ṣugbọn Olúwa mọ àwọn ohun tí a kọ, àti pẹ̀lú pe kò sí àwọn ènìyàn miràn ti ó mọ̀ èdè wa; àti nítorípé kò sí àwọn ènìyàn miràn ti o mọ̀ èdè wa, nitorinã ni o ti pèsè ọ̀na fun ìtúmọ̀ rẹ̀. Àwọn ohun wọnyĩ ní a sì kọ kí àwa ó le wẹ̀ asọ̀ wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin wa, tí wọn tì rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́. Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ohun wọ̀nyí ni a fẹ́ nípa àwọn arákùnrin wa, bẹ̃ni, àní ìmúpadà sí inú ìmọ̀ Krístì, wà ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó ti gbé inú ilẹ̀ nã rí. Kí Jésù Krístì Olúwa jẹ kí adura wọn ó gbà gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn; àti kí Ọlọ́run tí í ṣe Baba ranti májẹ̀mú èyítí ó ti dá pẹ̀lú idile Isráẹ́lì; àti ki o sì bùkúnfún wọn titi láé, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù Krístì. Àmín. 1 Mórónì ṣe àkékúrú àwọn ohun tí Étérì kọ—A tò ìtàn ìdílé Etérì lẹ́sẹlẹ́sẹ—A kò da èdè àwọn ara Járẹ́dì rú ni Ile-ìṣọ́ Bábélì—Olúwa ṣe ìlérí láti siwaju wọn dé ilẹ̀ daradara, yíò sì ṣe wọn ní orílẹ̀-èdè nlá. ÀTI nísisìyí emí, Mórónì, tẹ̀síwájú láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn olugbe àtijọ nnì tí a parunnípa ọwọ́ Oluwa nínú orílè-èdè apá àríwá yĩ. Emí sì mu ọ̀rọ̀ mi láti inú àwọn àwo mẹ́rìnlélógún nnì ti àwọn ènìyàn Límháì rí, èyítí wọn pè ni Ìwé ti Étérì. Bí mo sì ti lero pé apá kinni akọsile yĩ, èyítí ó sọ̀ nípa ìdásílẹ̀ ayé, àti nipa ti Ádámù, àti ọ̀rọ̀ láti ìgbà nã àní titi ó fi de ti ile-ìṣọ́ nla nã, àti ọ̀rọ̀ nipa ohunkóhun tí ó ṣẹ̀ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn titi di igba nnì, ní o kọ lãrín àwọn Jũ— Nitorinã, emí kò kọ àwọn ohun wọnnì tí ó ti ṣẹ̀ láti ìgbà Ádámù títí de ìgbà nnì; ṣùgbọ́n a kọ wọn lé ori àwọn àwo; ẹnikẹ́ni ti o bá sì rí wọn, oun nã ni yíò ní agbára láti gbà àkọsílẹ̀ ọrọ nã lẹ́kùnrẹ́rẹ́. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èmi kò kọ àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ nã lẹ́kùnrẹ́rẹ́, ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ nã ni èmi kọ, láti àkókò kíkọ́ ile-ìṣọ́ nnì titi dé àkókò tí a fi pa wọ́n run. Ni ti ọ̀nà yĩ sì ni emí ṣe kọ àkọsílẹ̀ nã. Ẹniti ó kọ àkọsílẹ̀ yĩ ni Étérì, ó sì jẹ́ ìran Koriántórì. Koriántórì ni ọmọ Mórọ̀n. Mórọ̀n sì ni ọmọ Étémù. Étémù sì ni ọmọ Áháhì. Áháhì sì ni ọmọ Sétì. Sétì sì ni ọmọ Ṣíblọ́nì. Ṣíblọ́nì sì ni ọmọ Kọ́mù. Kọ́mùsì ni ọmọ Koríántúmù. Koríántúmù sì ni ọmọ Ámnígádà. Ámnígádà sì ni ọmọ Áárọ́nì. Áárọ́nì sì jé ìran Hẹ́tì, ẹnití í ṣe ọmọ Héátómì. Héátómì sì ni ọmọ Líbù. Líbù sì ni ọmọ Kíṣì. Kíṣì sì ni ọmọ Kórómù. Kórómù sì ni ọmọ Léfì. Léfì sì ni ọmọ Kímù. Kímù sì ni ọmọ Moríántọ́nì. Moríántọ́nì s ì j ẹ́ ìran Ríplákíṣì. Ríplákíṣì sì ni ọmọ Ṣẹ́sì. Ṣẹ́sì sì ni ọmọ Hẹ́tì. Hẹ́tì sì ni ọmọ Kọ́mù. Kọ́mù sì ni ọmọ Koríántúmù. Koríántúmù sì ni ọmọ Émérì. Émérì sì ni ọmọ Ómérì. Ómérì sì ni ọmọ Ṣúlè. Ṣúlè sì ni ọmọ Kíbù. Kíbù sì ni ọmọ Òríhà, ẹniti í ṣe ọmọ Járẹ́dì; Járẹ́dì èyítí ó jáde wá pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ìdílé wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn míràn àti àwọn ìdílé wọn, láti ile-ìṣọ́ nla nnì, ní àkókò ti Olúwa dà èdè àwọn ènìyàn nã rú, tí ó sì búra nínú ìbínú rẹ̀ pé oun yíò fọn wọn ká kiri orí ilẹ̀ ayé; àti gẹ́gẹ́bí ọrọ Olúwa, a sì fọ́n àwọn ènìyàn nã ká. Àti pe arákùnrin Járẹ́dì nítorípé o jẹ ènìyàn títóbí tí ó sì lágbára, àti ẹniti o rí oju rere Olúwa lọ́pọ̀lọpọ̀, Járẹ́dì, arákùnrin rẹ̀, wí fún ún pé: Kígbe pé Olúwa, kí ó máṣe dà èdè wa rú kí àwa o sì ṣe àìgbọ́ ọ̀rọ̀ ara wa. O sì ṣe tí arákùnrin Járẹ́dì kígbe pe Olúwa, Olúwa sì ṣãnú fún Járẹ́dì; nitorinã ni òun kò sì dà èdè Járẹ́dì rú; òun kò sì dà Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀ rú. Nígbànã ni Járẹ́dì wi fun arákùnrin rẹ̀ pé: Tún kígbe pè Olúwa bí yíò bá mú ìbínú rẹ̀ kúrò lórí àwọn tí wọn jẹ ọ̀rẹ́ wa, kí ó má sì dà èdè wọn rú. O sì ṣe ti arákùnrin Járẹ́dì kígbe pè Olúwa, Olúwa sì ṣãnú fún àwọn ọ̀rẹ́ wọn àti àwọnìdílé wọn pẹ̀lú, tí òun kò sì dà wọ́n rú. O sì ṣe ti Járẹ́dì tún bá arákùnrin rẹ sọ̀rọ̀, tí ó wípé: Lọ kí ó sì bẽrè lọ́wọ́ Olúwa bóyá òun yíò lé wa kuro nínú ilẹ nã, bí òun yíò bá sì lé wa kúrò nínú ilẹ̀ nã, kígbe pè é nípa ibití àwa yíò lọ. Tani ó sì lè mọ̀ bóyá Olúwa yíò gbe wa lọ sínú ilẹ̀ èyítí ó dára jù lórí gbogbo ilẹ tí ó wà nínú ayé? Bí ó bá sì rí bẹ̃, ẹ jẹ́ kí àwa ó jẹ́ olótĩtọ́ sí Olúwa, kí àwa ó lè rí í gbà fún ìní wa. O sì ṣe ti arákùnrin Járẹ́dì kígbe pè Olúwa gẹ́gẹ́bí èyítí Járẹ́dì ti sọ fún un kí ó ṣe. O sì ṣe tí Olúwa gbọ́ arákùnrin Járẹ́dì, ó sì ṣãnú fún un, ó sì wi fún un pe: Lọ, kí o sì kó àwọn ọ̀wọ́ ẹ́ran rẹ jọ, àti akọ àti abo, kí ó sì mú lára gbogbo wọn ní onírúurú, àti pẹ̀lú nínú àwọn èso ayé gbogbo ni onírúurú; àti àwọn ìdílé rẹ; àti pẹ̀lú Járẹ́dì arákùnrin rẹ àti ìdílé rẹ̀; àti pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti àwọn ìdile wọn; àti àwọn ọ̀rẹ́ Járẹ́dì àti àwọn ìdílé wọn. Nígbàtí ìwọ bá sì ti ṣe báyĩ, ìwọ yíò lọ níwájú wọn, kọjá lọ sínú àfonífojì èyítí o wà ní ìhà apá àríwá. Níbẹ̀ ni èmi yíò sì pàdé rẹ, èmi yíò sì lọ níwájú rẹ sí inú ilẹ̀ èyítí ó dára jù gbogbo ilẹ̀ tí ó wà nínú ayé. Níbẹ̀ ni èmi yíò sì bùkún fún ọ àti irú ọmọ rẹ, emí ó sì gbé orílẹ̀ èdè nla soke si mi nínú irú ọmọ rẹ, àti nínú irú ọmọ arákùnrin rẹ, àti àwọn tí wọn yíò lọ pẹ̀lú rẹ. Kì yíò sì sí èyítí yíò tobi jù orilẹ ede tí emí yíò gbé dide fún èlò mi láti inú irú ọmọ rẹ, lórí ilẹ̀ ayé gbogbo. Báyĩ sí ni èmi yíò ṣe sí ọ nítorípé fun ìgbà pípẹ́ yĩ ni ìwọ́ fi kígbe pè mí. 2 Àwọn ará Járẹ́dì múrasílẹ̀ láti rìn ìrìn àjò wọn lọ sí ilẹ ilérí kan—Ilẹ̀ daradara ni í ṣe nínú èyítí àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ sìn Krístì tàbí kí a gbáwọn dànù—Olúwa bá arákùnrin Járẹ́dì sọ̀rọ̀ fún wákàtí mẹ́ta—Àwọn ara Járẹ́dì kàn àwọn ọkọ̀ ìgbájá—Olúwa ní kí arákùnrin Járẹ́dì ó sọ bí ìmọ́lẹ̀ yíò ṣe tàn nínú àwọn ọkọ̀ ìgbájá nã. O sì ṣe tí Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ìdílé wọn, àti pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ìdílé wọn, sọ̀kalẹ̀ lọ sínú àfonífojì èyítí ó wà ní ìhà apá àríwá, (orúkọ àfonífojì nã sì ni Nímrọ́dù, nítorítí a sọ ọ́ ní orúkọ ọdẹ alágbára nnì) pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn tí wọn ti kójọ papọ̀, akọ àti abo, ní onírúurú. Wọn sì dọdẹ pẹ̀lú láti mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run; wọn sì pèsè ohun èlò kan nínú èyítí wọn kó àwọn ẹja inú omi sí dani pẹ̀lú wọn. Wọn sì kó àwọn désérẹ́tì dání, ìtumọ̀ èyítí í ṣe oyin ìgàn; bayĩ sì ni wọn kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oyin dánì, àti onírúurú àwọn ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, onirũru irúgbìn gbogbo pẹ̀lú. O sì ṣe nígbàtí wọ́n tí sọ̀kalẹ̀ sínú afonifojì Nímrọ́dù tan Olúwa sọ̀kalẹ̀ wá bá arákùnrin Járẹ́dì sọ̀rọ̀; ó sì wà nínú ìkúukũ, arákùnrin Járẹ́dì kò sì rí i. O sì ṣe tí Olúwa pàṣẹ fúnwọn pé kí wọn ó lọ sínú aginjù, bẹ̃ni,sínú agbègbè ibiti ènìyàn kò dé rí. O sì ṣe tí Olúwa lọ níwájú wọn, ó sì bá wọn sọrọ bí òun ṣe dúró nínú ìkùukũ, o sì sọ fún wọn ibití wọn yio rìn ìrìnajo si. O sì ṣe tí wọn rìn ìrìnàjò nínú aginjù, tí wọ́n sì kàn àwọn ọkọ̀ ìgbájá, nínú èyítí wọ́n là ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi nlá kọjá, a sì ndari wọn títí nípa ọwọ́ Olúwa. Olúwa kò sì gbà fún wọn láti dúró ní ìkọjá òkun tí ó wà nínú aginjù, sugbọn ó fẹ́ kí wọn ó jáde wá àní sínú ilẹ̀ ìlérí, èyítí ó jẹ́ àṣàyàn jù gbogbo ilẹ̀ lọ, èyítí Olúwa Ọlọ́run ti fi pamọ́ dè àwọn ènìyàn olódodo. O sì ti búra nínú ìbínú rẹ̀ pẹ̀lú arákùnrin Járẹ́dì, pé ẹnití yíò bá ni ilẹ̀ ìlérí yĩ ní ìní, láti igba nã lọ titi láé, gbọ́dọ̀ sìn òun, Ọlọ́run kanṣoṣo tí í ṣe otitọ, tabi kí a gbawọ́n dànù nígbàtí èkúnrẹ́rẹ́ ìbínú rẹ̀ yíò dé bá wọn. Àti nísisìyí, a lè ri àwọn ìpinnu Ọlọ́run nipa ilẹ̀ yĩ, pe ilẹ̀ ìlérí ni; àti pé ọrílẹ̀ èdè èyíówù ti ó bá ní i ní ìní yíò sìn Ọlọ́run, bíkòṣebẹ̃ a ó gbáwọn dànù nígbàtí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbínú rẹ̀ yíò dé bá wọn. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbinu rẹ̀ yíò sì dé bá wọn nígbàtí wọ́n bá ti gbó nínú àìṣedẽdé. Nítorí ẹ kíyèsĩ, ilẹ̀ yĩ jẹ́ èyítí a ṣàyàn jù gbogbo ilẹ̀ lọ; nítorí èyí ẹnití ó bá ní i ní ìní yíò sìn Ọlọ́run bikosebẹ̃ a ó gbáwọn dànù; ó sì jẹ́ àṣẹ Ọlọ́run títí ayé. A kò sì ni gbáwọn dànù, bikòṣe ní àkókò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ aiṣedede lãrín àwọn ọmọ inu ilẹ̀ nã. Eleyi sì tọ̀ yín wa, A! ẹyin Kèfèrí, kí ẹyin ó lè mọ̀ àṣẹ Ọlọ́run—kí ẹyin o lè ronúpìwàdà, àti láti má tẹ̀síwájú nínú àwọn àìṣedédé yín di ìgbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ yíò dé, kí ẹyin ó máṣe mú ẹkunrẹrẹ ìbínú Ọlọ́run dé bá yín gẹ́gẹ́bí àwọn tí ngbé inú ilẹ̀ nã ti ṣe ní ìgbà ìṣájú. Ẹ kíyèsĩ, ilẹ̀ aṣayan ni eyí jẹ́, orílè èdè èyíkéyĩ tí yíò ní i ní ìní yíò wà ní òmìnira kúrò nínú ìdè, àti kúrò nínú ìgbèkùn, àti kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn orilẹ ede miràn lábẹ́ ọ̀run, bí wọn yio bà sìn Ọlọ́run ilẹ nã, ẹnití í ṣe Jésù Krístì, ẹniti á ti fihàn nípa àwọn ohun tí àwa ti kọ. Àti nísisìyí emí tẹ̀síwájú pẹ̀lú àkọsílẹ̀ mi; nitori kíyèsĩ, o sì ṣe tí Olúwa sì mú Járẹ́dì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde àní dé òkun nla nnì èyítí ó pín àwọn ilẹ̀ nã. Bí wọn sì ti dé ibi òkun nã wọn pàgọ́ wọn; wọ́n sì pè orukọ ibẹ̀ ni Moriánkúmérì; wọ́n sì ngbé inú àgọ́, wọ́n sì gbé inú àgọ́ leti òkun fún ìwọ̀n ọdún mẹrin. O sì ṣe ni òpin ọdún mẹ́rin ni Olúwa tún wá sí ọ́dọ̀ arákùnrin Járẹ́dì, tí ó sì duro nínú ìkũkũ tí ó sì bá a sọ̀rọ. Fún ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta ni Olúwa bá arákùnrin Járẹ́dì sọ̀rọ̀, tí ó sì bá a wí nítorípé kò rántí láti kígbe pè orúkọ Olúwa. Arákùnrin Járẹ́dì sì ronúpìwàdà ohun búburú tí ó ti ṣe, ó sì kígbe pè orukọ Olúwa nitori àwọn arákùnrin rẹ̀ ti wọn wà pẹ̀lú rẹ̀. Olúwa sì wí fún un pe: Ẹmí yíò dáríjì ọ́ àti àwọn arákùnrin rẹ níti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn; sùgbọ́n ìwọ kò gbọ́dọ̀ dẹ́ṣẹ̀ mọ́, nítorítí ìwọ gbọ́dọ̀ ranti pé Ẹ̀mí mi ki yíò bá ènìyàn jà ìjàkadì títí; nítorí eyi, bí ìwọ yíò bá dẹ́ṣẹ̀ titi ìwọ yíò fi gbó nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, aó ké ọ kúrò lọ́dọ̀ Olúwa. Àwọn wọ̀nyí sì ní èrò mi nipa ilẹ̀ tí emí yíò fi fún ọ́ fún ìní rẹ; nítorítí yíò jẹ ilẹ̀ àsàyàn jù ilẹ̀ gbogbo lọ. Olúwa sì wípe: Lọ ṣiṣẹ́ kí ó sì kàn, ní ọ̀nà kannã tí ìwọ kàn àwọn okọ̀ ìgbájá ní ìgbà iṣaju. O sì ṣe tí arákùnrin Járẹ́dì sì lọ ṣiṣẹ́, àti àwọn arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n sì kàn àwọn ọkọ̀ ìgbájá ní ọ̀nà kannã tí wọn tí kàn wọ́n ní igbà ìṣajú, gẹ́gẹ́bí Olúwa ti fi kọ́ wọn. Wọ́n sì kéré, wọn sì fúyẹ́ lórí omi, àní bí ẹyẹ ti ifúyẹ́ lórí omi. A sì kàn wọ́n lọ́nà tí omi kò lè jò jáde kúrò nínú wọn, àní ti wọ́n gbà omi dúró bí àwo; abẹ rẹ̀ kò sì lè jò omi jáde bí ti àwo; àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sí lè jò omi jáde bí ti àwo; àwọn igun rẹ̀ sì rí ṣónṣó; ori rẹ̀ kò sí lè jò omi jáde bí tí àwo; gígùn rẹ̀ sì tó gígùn igi; ilẹ̀kùn rẹ̀, nígbàtí wọn tì í, kò sì lè jò omi jáde bí ti àwo. O sì ṣe tí arákùnrin Járẹ́dì kígbe pè Olúwa, tí ó wípé: A! Olúwa, emí ti ṣe iṣẹ́ èyítí ìwọ pa láṣẹ fun mi, emí sì ti kàn àwọn ọkọ̀ ìgbájá nã gẹgẹbi ìwọ ti tọ́ mi sọ́nà. Sì kíyèsĩ, A! Olúwa, kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú wọn; níbo ni àwa yio tukọ̀ lọ? Àti pẹ̀lú àwa yíò parun, nítorípé àwa kò lè mí nínú wọn, bíkòṣepé afẹ́fẹ́ wà nínú wọn; nitorinã àwa yíò parun. Olúwa sì wí fún arákùnrin Járẹ́dì pe: Kíyèsĩ, ìwọ yíò dá ihò lu sí ori rẹ̀ àti pẹ̀lú ní abẹ́ rẹ; nígbàtí ìwọ bá sì ṣaláìní afẹ́fẹ́ ìwọ yíò ṣí ihò nã sílẹ̀ kí ó sì rí afẹ́fẹ́ gbà. Bí ó bá sì rí bẹ̃ tí omi wọle bá yín, kíyèsĩ, ìwọ yíò dí ihò nã, kí ìwọ ó ma bã parun nínú ìró omi nã. O sì ṣe tí arákùnrin Járẹ́dì ṣe bẹ̃, gẹ́gẹ́bí Olúwa ti pa láṣẹ. O sì tún kígbe pe Olúwa wípé: A! Olúwa, kíyèsĩ emí ti ṣe é àní bí ìwọ ti pa á láṣẹ fún mi; emí sì ti pèsè àwọn ọkọ̀ nã sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn mi, sì kíyèsĩ kò sí ìmọ́lẹ̀ ní inú wọn. Kíyèsĩ, A! Olúwa, njẹ ìwọ ó ha jẹ́ kí àwa ó là agbami nla yĩ kọjá nínú okùnkùn bí? Olúwa sì wí fún arákùnrin Járẹ́dì pe: Kíni ìwọ fẹ kí emí ó ṣe kí ìwọ́ o lè ní imọlẹ nínú àwọn ọkọ̀ rẹ? Nitori kíyèsĩ, ìwọ kò lè ní fèrèsé, nítorítí wọn ó fọ́ sí wẹ́wẹ́, bẹ̃ni iwọ́ kò gbọ́dọ̀ gbé ina lọ́wọ́ pẹlú rẹ, nítorí ìwọ kò gbọ́dọ̀ lọ niti ìmọ́lẹ́ iná. Nitori kíyèsĩ ìwọ yíò rí bí erinmi lãrín òkun; nitori àwọn ìrú ìbìlù omi gíga yíò kọlũ yín. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, emí yíò padà mú ọ jáde kúrò nínú ìsàlẹ̀ okun nã; nítorítí láti ẹnu mi wá ni àwọn èfũfù ti jáde wá, àti àwọn òjò àti àwọn ìró omi, èmi ni ó rán wọn. Sì kíyèsĩ, emí ti pèsè rẹ sílẹ̀ de àwọn ohun wọ̀nyí; nítorí ìwọ kò lè kọjá nínú ọ̀gbun nla yĩ afi bí emí bá pèsè rẹ sílẹ̀ dè àwọn ìbìlù omi òkun, àti àwọn èfũfù tí ó ti jáde lọ, àti àwọn iro omi ti yíò wã. Nitorinã kini ìwọ fẹ́ kí emí ó pèsè fún ọ kí ìwọ ó lè ní ìmọ́lẹ̀ nígbàtí ó bá wà ni gbígbémì nínú ìsàlẹ̀ òkun? 3 Arákùnrin Járẹ́dì rí ìka Olúwa bí ó ṣe nfọwọ́kàn àwọn òkúta wẹ́wẹ́ mẹ́rìndínlógún—Krístì fí ara rẹ̀ ní ẹ̀mí hàn arákùnrin Járẹ́dì—Ákò lè dènà mọ́ àwọn ẹniti ó ni ìmọ̀ pípé láti dá ìbòjú kọjá—Olúwa pèsè àwọn olùtúmọ̀ láti sọ àkọsílẹ̀ àwọn ara Járẹ́dì di mímọ̀. Ó sì ṣe tí arákùnrin Járẹ́dì, (nísisìyí iye àwọn ọkọ̀ tí wọn tí pèsè jẹ́ mẹ́jọ) kọjá lọ sórí òkè, èyítí wọn npè ní òkè Ṣẹ́lẹ́mù, nítorítí ó ga púpọ̀, ó sì yọ́ òkúta wẹ́wẹ́ mẹ́rìndínlógún jáde láti inú òkúta nlá kan; wọ́n sì funfun wọ́n sì mọ́ gãra, àní bĩ dígí dídán gẽre; ó sì ko wọn nínú ọwọ́ rẹ̀ lórí òkè nã, ó sì tún kígbe pè Olúwa, wípé: A! Olúwa, ìwọ ti wí i pé àwọn ìró omi yíò yíwa ká. Nísisìyí kíyèsĩ, A! Olúwa, kí ó má sì ṣe bínú sí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ nitori àìlera rẹ̀ níwájú rẹ̀; nítorítí àwa mọ̀ pé mímọ́ ni ìwọ í ṣe, o sì ngbé nínú àwọn ọ̀run, àti pé àwa jẹ aláìtóye níwájú rẹ; nitori ìṣubú, ìwà wa jẹ́ èyítí ó burú títí; bíótilẹ̀ríbẹ̃, A! Olúwa, ìwọ ti fún wa ní òfin pé àwa gbọ́dọ̀ ké pè ọ́, kí àwa ó lè rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú wa. Kíyèsĩ, A! Olúwa, ìwọ ti kọlũ wà nitori àìṣedẽdé wa, o sì ti lé wa kákiri, àti fun àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdun wọnyĩ ni áwa wà nínú aginjù; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ìwọ ti sãnú fún wa. A! Olúwa, bojú wò mi nínú ãnú, kí ó sì mú ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ yĩ, kí o má sì jẹ́ kí wọn ó dá òkun nlá yĩ kọjá nínú òkùnkùn; ṣùgbọ́n wò àwọn ohun wọ̀nyí tí èmi tí yọ́ láti ìnu òkúta. Ẹmí sì mọ̀, A! Olúwa, pé ìwọ ní gbogbo agbara, ìwọ sì lè ṣe ohunkóhun tí ó bá wù ọ́ fún ànfàní ènìyàn; nitorinã fọwọ́kàn àwọn òkúta wẹ́wẹ́ yĩ, A! Olúwa, pẹ̀lú ìka rẹ, kí ó sì ṣé wọn kí wọn ó lè máa tàn ìmọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn; wọn yíò sì tàn ìmọ́lẹ̀ fún wa nínú àwọn ọkọ̀ tí àwa ti pèsè, kí àwa ó lè ní ìmọ́lẹ̀ nígbàtí àwa yíò kọ́já nínú òkun nã. Kíyèsĩ, A! Olúwa, ìwọ lè ṣe èyí. Àwa mọ̀ pé ìwọ lè fi agbára nlá hàn, èyítí ó dàbíi pé o kere sí òye àwọn ọmọ ènìyàn. O sì ṣe nígbàtí arákùnrin Járẹ́dì ti sọ àwọn ọrọ wọ̀nyí, kíyèsĩ, Olúwa nà ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì fọwọ́kàn àwọn òkúta wẹ́wẹ́ nã pẹ̀lú ìka rẹ̀ lọ́kọ̣́kan. Ìbòjú sì ká kúrò lójú arákùnrin Járẹ́dì, ó sì rí ìka Olúwa; ó sì dabi ìka ènìyàn, tí o ni ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀; arákùnrin Járẹ́dì sì wólulẹ̀ níwájú Òluwa, nítorítí ìbẹ̀rù bọ́ mọ́lẹ̀. Olúwa sì rí i pé arákùnrin Járẹ́dì ti ṣubú lulẹ̀; Olúwa sì wì fún un pé: Dìde, kíni ìdí rẹ̀ ti ìwọ ṣe ṣubú? O sì wí fún Olúwa pé: Mo rí ìka Olúwa, ẹ̀rù sì bà mí pé yíò kọlũ mí; nítorítí emí kò mọ̀ pé Olúwa ní ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀. Olúwa sì wí fún un pe: Nitori ìgbàgbọ́ rẹ ìwọ ti rí i pé èmi yíò gbé ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ wọ̀; kò sì sí ẹnití ó wa sí iwájú mí pẹ̀lú ìrú ìgbàgbọ́ tí ó tayọ báyĩ rí bí ìwọ ti ṣe; nítorí bí kò bá rí bẹ̃ ìwọ kì bá tí rí ìka mi. Njẹ ìwọ ha rí ju èyí bí? O sì dáhùn pé: Rara; Olúwa, fi ara rẹ hàn sí mi. Olúwa sì wí fún un pé: Njẹ ìwọ yíò ha gba àwọn ọ̀rọ̀ tí èmi yíò sọ gbọ́ bí? O sì dáhùn pé: Bẹ̃ni, Olúwa, emí mọ̀ pé òtítọ́ ní ìwọ nwí,nítorípé Ọlọ́run òtítọ́ ní ìwọ í ṣe, ìwọ kò sì lè purọ́. Nígbàtí ó sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ẹ kíyèsĩ, Olúwa fí ara rẹ̀ hàn sí i, ó sì wípé: Nítorípé ìwọ mọ̀ àwọn ohun wọ̀nyí, a rà ọ́ padà kúrò nínú ìṣubú; nítorinã a mú ọ padà wá sí ọ̀dọ̀ mi; nitorinã èmi fi ara mi hàn sí ọ. Kíyèsĩ, èmi ni ẹni ti a pèsè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé láti rà àwọn ènìyàn mi padà. Kíyèsĩ, èmi ni Jésù Krístì. Emí ni Bàbá àti Ọmọ. Nínú mi ni gbogbo ènìyàn yiò ní ìyè, èyítí ó wà fún ayérayé, àní àwọn tí yíò gbà orúkọ mi gbọ́; wọn yíò sì dì ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi. Èmi kò sì fi ara mi hàn fún ènìyàn tí emí dá rí, nítorítí ènìyàn ko gbà mi gbọ́ rí gẹ́gẹ́bí ìwọ ti ṣe. Njẹ ìwọ ha rí i pé a dá ọ ní àwòrán ara mi bí? Bẹ̃ni, àní gbogbo ènìyàn ni a dá ní àtètèkọ́ṣe ní àwòrán ara mi. Kíyèsĩ, ara yĩ, èyíti ìwọ nwò yĩ, jẹ́ ara ti ẹ̀mí mi; mo sì dá ènìyàn ní àwòrán ara ti ẹ̀mí mi; àní gẹ́gẹ́bí èmi sì ti farahàn sí ọ ní ti ẹ̀mí ni èmi ó farahàn sí àwọn ènìyàn mi ní ti ara. Àti nísisìyí, nítorípé emí, Mórónì, ti ṣọ wípé emí kò lè ṣe àkọsílẹ̀ nipa àwọn ohun tí wọ́n ti kọ wọ̀nyí, nitorinã ó tó fún mi kí èmi ó wípé Jesu fi ara rẹ̀ han sí ọkunrin yĩ nítí ẹ̀mí, àní gẹgẹbi ó ti farahàn nínú ara kánnã sí àwọn ará Nífáì. O sì jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún un àní gẹ́gẹ́bí ó ti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ara Nífáì; gbogbo èyí ni ó ṣe, kí ọkunrin yĩ lè mọ̀ pé Ọlọ́run ni oun í ṣe, nitori àwọn iṣẹ́ nlá-nlà tí Olúwa ti fi hàn sí i. Àti nítorí ìmọ̀ tí ọkùnrin yĩ ní a kò lè dènà mọ́ ọ láti bojúwò láti inu ìbòjú nã; ó sì ri ìka Jésù, nígbàtí ó sì ríi, ó ṣubú nínú ẹ̀rù; nítorítí ó mọ̀ pé ìka Olúwa ni; kò sì gbàgbọ́ nì kan, nítorítí ó mọ̀, ní áìṣiyèméjì ohunkóhun mọ. Nítorí eyi, nítorípé ó ní imọ pipe nipa Ọlọ́run, a kò lè dènà mọ́ ọ kúrò nínú ìbòjú; nítorínã ó rí Jesu; òn sì jíṣẹ́ iranṣẹ fún un. O sì se ti Olúwa wí fún arákùnrin Járẹ́dì pé: Kíyèsĩ, ìwọ́ kì yíò jẹ́ kí àwọn ohun wọnyĩ tí ìwọ ti ri àti ti ìwọ ti gbọ kọ́já lọ́ sínú ayé, títí di akòkò tí mbọ̀wá tí èmí yíò ṣe orúkọ mi lógo nípà ti ara; nítorí eyi, ìwọ yio pa àwọn ohun wọ̀nyí ti ìwọ ti ri àti tí ìwọ ti gbọ mọ́ nínú ọkàn rẹ, kí ìwọ má sì ṣe fíhàn ẹnikẹ́ni. Sì kíyèsĩ, nígbàtí ìwọ yíò wá sí ọ̀dọ̀ mi, ìwọ yíò kọ wọ́n, ìwọ yíò sì fi èdìdí dì wọ́n, kí ẹnikẹ́ni ó má lè ṣe ìtumọ̀ wọn; nítorítí ìwọ yíò kọ wọ́n ní èdè ti ẹnikẹ́ni kò lè kà. Sì kíyèsĩ, àwọn òkúta méjì yĩ ni emí yíò fi fún ọ, ìwọ yíò sì fi èdìdí dì àwọn nã pẹ̀lú àwọn ohun tí ìwọ yíò kọ. Nítorí kíyèsĩ, èdè tí ìwọ yíò kọ ní emí ti dàrú; nítorí èyí ní emí yíò mú kí àwọn òkúta wẹ́wẹ́ yĩ mú àwọn ohun ti ìwọ yíò kọ tobi ní ojú àwọn ènìyàn nígbàtí àkókò bá tó fun mi. Nígbàtí Olúwa sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọnyĩ, ó fi í hàn sí arákùnrin Járẹ́dì, gbogbo àwọn ẹnití ngbé inu ayé, ní tẹlẹri, àti gbogbo àwọn tí yíò gbé inu rẹ; kò sì dènà mọ́ ọ láti rí wọn, àní títí dé ìkangun ayé. Nítorí ó ti wí fún un ní àwọn àkókò ìṣãjú, pé tí ó bá gbà òun gbọ́ òun lè fí ohun gbogbo hàn án—a ó sì fi wọn hàn án; nítorínã Olúwa kò lè dènà ohunkóhun mọ́ ọ, nítorítí ó mọ̀ pé Olúwa lè fi ohun gbogbo hàn sí oun. Olúwa sì wí fún un pe: Kọ àwọn ohun wọnyĩ kí ó sì dì wọ́n ni èdìdí; èmi yíò sì fi wọ́n hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn nígbàtí àkókò bá tó fún mi. O sì ṣe tí Olúwa pàṣẹ fún un láti dì àwọn okuta wẹ́wẹ́ méjì nã èyítí ó ti gbà ní èdìdí, kí ó má sì fi wọ́n hàn, titi Olúwa yíò fi wọ́n hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn. 4 Olúwa pàṣẹ fún Mórónì láti dì àwọn ohun tí arákùnrin Járẹ́dì kọ ní èdìdí—À kò ni fí wọ́n hàn titi àwọn ènìyàn yíò fi ní ìgbàgbọ́ àní bí ti arákùnrin Járẹ́dì—Krístì paṣẹ fún àwọn ènìyàn kí wọn ó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ gbọ—A pàṣẹ fún àwọn ènìyàn láti ronúpìwàdà, gbà ìhìn-rere gbọ́, kí wọn ó sì di ẹni ìgbàlà. Olúwa sì pàṣẹ fún arákùnrin Járẹ́dì láti sọ̀kalẹ̀ lọ kúrò lórí òkè nã kuro níwájú Olúwa, kí ó sì kọ àwọn ohun tí ó ti rí; a sì kã lẽwọ̀ láti mú wọn wá sí òdọ̀ àwọn ọmọ ènìyàn titi di ẹ̀hìn ìgbà ti a ó gbé e sókè lórí àgbélebú; nítorí ìdí èyi sì ni ọba Mòsíà fi pa wọ́n mọ́, pé kí wọn ó ma jáde sí ayé titi di ẹ̀hìn ìgbà tí Krístì yíò fi ara rẹ̀ hàn si àwọn ènìyàn rẹ̀. Àti lẹ́hìn tí Krístì sì ti fi ara rẹ̀ hàn nítọ́tọ́ sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó pàṣẹ pé kí wọn ó fi wọn hàn sí wọn. Àti nísisìyí, lẹ́hìn àkókò nã, gbogbo wọn ni ó ti rẹ̀hìn nínú igbàgbọ́; kò sì sí ẹnikẹ́ni afi àwọn ará Lámánì, àwọn nã ti kọ̀ ìhìn-rere Krístì; nitorinã a pa á láṣẹ fún mi pe, kí èmi ó tún gbé wọn pamọ́ sínú ilẹ̀. Ẹ kíyèsĩ, mo ti kọ àwọn ohun nã sí ori àwọn àwo yĩ, àwọn ohun tí arákùnrin Járẹ́dì rí; kò sì sí ohun tí ó tóbi tó báyĩ rí tí a fihàn tó àwọn ohun tí a fíhàn sí arákùnrin Járẹ́dì. Nítorí èyí Olúwa ti pa á láṣẹ fún mi láti kọ wọ́n; emí sì ti kọ wọ́n. O sì paṣẹ fún mi pé ki èmi ó dì wọn ní èdìdí; ò sì tún ti pàṣẹ pé kí èmi ó dì itumọ̀ rẹ̀ ní èdìdí; nítorí eyi ni èmi ṣe dì àwọn atúmọ̀ ní èdìdí, gẹ́gẹ́bí àṣẹ Olúwa. Nítorítí Olúwa wí fún mi pé: Wọn kò ní jáde lọ si ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí titi dí ọjọ nã tí wọn yíò ronúpìwàdà kúrò nínú àìṣedẽdé wọn, tí wọn ó sì di aláìléerí níwájú Olúwa. Àti ní ọjọ́ nã nínú èyítí wọ̀n yíò fi ìgbàgbọ́ bá mi lò, ni Olúwa wí, àní bí arákùnrin Járẹ́dì ti ṣe, kí wọn ó lè di ìyásímímọ́ nípasẹ̀ mi, nígbànã ní emí yíò fí àwọn ohun tí arákùnrin Járẹ́dì ti rí hàn sí wọn, àní de fífihàn sí wọn gbogbo àwọn ìfihàn mi, ni Jésù Krístì wí, Ọmọ Ọlọ́run, Baba àwọn ọ̀run àti ti ayé, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn. Ẹnití yíò bá sì bá ọ̀rọ̀ Olúwa jà, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú; ẹniti yíò bá sì sẹ́ àwọn ohun wọ̀nyí, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú; nítorítí èmí kò ní fi ohun tí ó tóbi jù èyĩ lọ hàn síwọn, ni Jésù Krístì wí; nítórítí emí ni ẹni nã ẹnití nsọ̀rọ̀. Àti ní àṣẹ mi àwọn ọ̀run dì ṣíṣísílẹ̀ àtí pípadé; àti ní ọ̀rọ̀ mi ayé yíò mì; àti ní àṣẹ mi àwọn ẹnití ngbé inú rẹ̀ yíò kọjá lọ, àní bí ẹni pé nípasẹ̀ iná. Àti ẹnití kò bá gbà àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́ kò gbà àwọn ọmọ-ẹ̀hìn mi gbọ́; bí ó bá sì rí bẹ̃ pé èmi kò sọ̀rọ̀, ẹ dájọ́; nítorítí ẹyin yíò mọ̀ pé èmi ní ẹninã tí ó sọ̀rọ̀, ní ọjọ́ ìkẹhìn. Sugbọn ẹnití ó bá gbà àwọn ohun wọ̀nyí tí èmi ti sọ gbọ́, òun ni emí yíò bẹ̀wò pẹ̀lú ìṣípayá Ẹmí mi, òun yíò sì mọ̀ yíò sì ṣe ìjẹ́risí rẹ̀. Nitori ti Ẹ̀mi mi ni òun yíò mọ̀ pé òtítọ́ ni àwọn ohun wọ̀nyí; nítorítí wọn a máa yí ọkàn àwọn ènìyàn padà láti ṣe rere. Ohunkóhun tí ó bá sì nyí ọkàn àwọn ènìyan padà láti ṣe rere wá láti ọwọ́ mi; nitoripe rere ko wá láti ọwọ́ ẹnikẹ́ni bíkòṣe láti ọwọ́ mi. Èmi kannã ni ó ndarí àwọn ènìyàn láti ṣe rere; ẹnití kò bá ní gbà àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́ kì yíò gbà mí gbọ́—pé èmi ni; ẹnití kò bá sì gbà mí gbọ́ kì yíò gbà Baba gbọ́ ẹnití ó rán mi. Nítorí kíyèsĩ, èmi ni Baba, èmi ni ìmọ́lẹ̀, àti ìyè, àti òtítọ́ ayé. Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi, A! ẹ̀yin Kèfèrí, emí yíò si fi àwọn ohun tí ó tóbijù hàn sí yín, imọ nã èyítí a ti gbé pamọ́ nítorí àìgbàgbọ́. Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi, A! ẹ̀yin ìdílé Ísráẹ́lì, a ó sì fi hàn sí ọ bí Baba ti ṣe ìpèsè àwọn ohun nlá fún ọ, láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé; kò sì di ìfihàn sí ọ, nitorí àìgbàgbọ́. Ẹ kíyèsĩ, nígbàtí ẹ̀yin bá fà ìbòjú àìgbàgbọ́ nnì ya èyítí ó mú ki ẹ̀yin ó wà nínú ipò ìwà búburú yin nnì, àti ọkàn tí ó sé le, àti ọkàn tí ó fọ́jú, nígbànã ni àwọn ohun nlá èyítí ó yanilẹ́nu tí a ti gbé pamọ́ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé kúrò lọ́dọ̀ yín—bẹ̃ni, nígbàtí ẹ̀yin bá ké pé Bàbá ní orúkọ mi, pẹ̀lú ìrora ọkàn àti èmí ìròbìnújẹ́, nígbànã ní ẹ̀yin yio mọ̀ pé Bàbá ti rántí májẹ̀mú nã èyítí ó ti bá àwọn baba yín da, A! ìwọ idile Isráẹ́lì. Nigbanã ni àwọn ìfihàn mi èyítí mo ti mú kí ìránṣẹ́ mi Jòhánnù ó kọ yíò si di fífihàn ní kedere sí gbogbo ènìyàn. Ẹ rántí, nígbàtí ẹ̀yin bá rí àwọn ohun wọ̀nyí, ẹ̀yin yíò mọ̀ pé àkókò nã ti dé tán tí wọn yíò di mímọ̀ nínú ìṣe tí ó lágbára. Nitorinã, nígbàtí ẹ̀yin yíò gbà àkọsílẹ̀ yĩ ẹ̀yín yíò mọ̀ pé iṣẹ́ Baba ti bẹ̀rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀. Nítorínã, ẹ ronúpìwàdà gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé, kí ẹ sì wá sí ọ́dọ̀ mi, kí ẹ sì gbà ìhìn-rere mi gbọ́, kí a sì ṣe ìrìbọmi fún yin ní orúkọ mi; nítorítí ẹnití ó bá gbàgbọ́ tí a sì ṣe ìrìbọmi fún ni à ó gbàlà; sùgbọ́n ẹnití kò bá gbàgbọ́ ni a ó dálẹ́bi; àwọn àmì yíò sì máa tẹ̀lé àwọn tí ó gbà orukọ mi gbọ́. Alábùkún-fún sì ni ẹni nã tí ó bá wà ní ìsòtítọ́ sí orukọ mi ni ọjọ́ ìkẹhìn, nítorítí a ó gbé e sókè láti máa gbé nínú ìjọba ti a ti pèsè sílẹ̀ fún un láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Ẹ sì kíyèsĩ èmi ni ó wíi. Àmín. 5 Àwọn ẹlẹ̃rí mẹta àti iṣẹ́ nã fúnrarẹ̀yíò duro gégẹ́bí ẹ̀rí otitọ Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Àti nísisìyí emí, Mórónì, ti kọ àwọn òrọ̀ tí a pa laṣẹ fún mi láti kọ, gẹ́gẹ́bí èmi ti rántí; èmi sì ti sọ fún ọ níti àwọn ohun ti emí ti dì ní èdìdí; nítorínã máṣe fọwọ́kàn wọ́n fún kí ìwọ ó ṣe ìtúmọ̀ wọn; nítorítí a ti ka ṣíṣe eleyĩ sí ẽwọ̀ fún ọ, bíkòṣe ní àkókò tí yíò jẹ́ ọgbọ́n nínú Ọlọ́run. Àti kíyèsĩ, ìwọ lè ní ànfànì láti fi àwọn àwo nã hàn sí àwọn tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú iṣẹ́ yì í jáde wá; Sí àwọn mẹ́ta ni a ó sì fihàn nípa agbára Ọlọ́run; nítorí eyi wọn yíò mọ̀ dájúdájú pé àwọn ohún wọ̀nyí jẹ òtítọ́. Àti láti ẹnu àwọn ẹlẹ́èrí mẹ́ta ni á ó fi àwọn ohún wọ̀nyí lélẹ̀; àti ẹ̀rí àwọn mẹta, àti iṣẹ́ yĩ, nínú èyítí a ó fi agbára Ọlọ́run hàn àti ọ̀rọ̀ rẹ̀, nípa àwọn èyítí Baba, àti Omọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́ yíò ṣe àkọsílẹ̀—gbogbo èyĩ ní yìò sì dúró ní ìjẹ̃ri si ayé ní ọjọ́ ìkẹhìn. Bí wọ́n bá sì ronúpìwàdà tí wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Bàbá ní orúkọ Jésù, a ó gbà wọ́n sínú ìjọba Ọlọ́run. Àti nísisìyí, bí èmi kò bá ní àṣẹ ní ti àwọn ohun wọ̀nyí, ẹ dajọ; nítorí ẹ̀yin yíò mọ̀ pé mo ní àṣẹ nígbàtí ẹ̀yin yíò rí mi, àwa yíò sì dúró níwájú Ọlọ́run ni ọjọ́ ìkẹhìn. Àmín. 6 Afẹ́fẹ́ gbé àwọn ọkọ̀ ìgbájá àwọn ara Járẹ́dì lọ́ sì ilẹ̀-ìlérí—Àwọn ènìyan nã yìn Olúwa fún ore rẹ̀—A yàn Òríhà bí ọba lé wọn lórí—Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀ kú. Àti nísisìyí emí, Mórónì, tẹ̀síwájú láti sọ nípa àkọsílẹ̀ nipa Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀. O sì ṣe lẹ́hìn tí Olúwa ti pèsè àwọn òkúta wẹ́wẹ́ èyítí arákùnrin Járẹ́dì ti gbé lọ sí ori òkè, arákùnrin Járẹ́dì sọ̀kalẹ̀ lọ kúrò lórí òkè nã, ó sì kó àwọn òkúta wẹ́wẹ́ nã lọ sínú àwọn ọkọ̀ nã èyítí wọ́n ti pèsè sílẹ̀, ọ̀kan ní ìpẹ̀kun kọ̣́kan; ẹ sì kíyèsĩ, wọ́n sì tàn ìmọ́lẹ̀ sí inú àwọn ọkọ̀ nã. Báyĩ si ni Olúwa mú kí àwọn òkúta wẹ́wẹ́ ó tàn nínú òkùnkùn láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé, kí wọn ó má kọjá nínú omí nlá nã nínú òkùnkùn. O sì ṣe nígbàtí wọ́n ti pèsè onírúurú onjẹ sílẹ̀, ti wọn ó jẹ nígbátí wọn bá wà lórí omi, àti onjẹ fún àwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn àti àwọn agbo ẹran wọn, àti ẹranko-kẹ́ranko tàbí ẹyẹ-kẹ́yẹ tí wọn yíò kó pẹ̀lú wọn—ó sì ṣe nígbatí wọ́n ti ṣe gbogbo ohun wọ̀nyí wọn wọ̀ inú àwọn ọkọ̀ tabí àwọn ọkọ̀ ìgbájá wọn lọ, wọ́n ṣí jáde lọ sínú òkun, wọ́n sì fi ara wọn lé Olúwa Ọlọ́run wọn lọ́wọ́. O sì ṣe tí Olúwa Olọ́run mú kí afẹ́fẹ́ tí ó lágbára ó fẹ́ lórí omi nã, sí apá ibití ilẹ̀-ìlérí nã wà; báyĩ sì ni a ngbá wọn kiri lórí ìbìlù-omi òkun nã níwájú afẹ́fẹ́. O sì ṣe ti òkun bò wọn mọ́lẹ̀ nínú jíjìn rẹ̀ ní igba pupọ, nitori àwọn ìbìlù-omi gíga tí ó nbì jáde lórí wọn, àti àwọn ẹ̀fũfù líle nla ti nfẹ́ nítorítí afẹ́fẹ́ nã nfẹ ní lílelíle. O sì ṣe nígbàtí a ti bò wọn mọ́lẹ̀ nínú jíjìn òkun nã kò sí omi ti ó lè pa wọ́n lara, nítorípé àwọn ọkọ̀ wọn kò lè jò omi jáde bí ti àwo, àti pẹ̀lú wọn kò lè jò omi àní gẹ́gẹ́bí bí ti ọkọ Nóà; nitorínã nígbàtí omi púpọ̀ yí wọn ká wọn sì kígbe pè Olúwa, òun sì mú wọn jáde padà sí órí omi nã. O sì ṣe tí afẹ́fẹ́ nã kò dẹ́kun fífẹ́ sí apá íbití ilẹ̀-ìléri nã wà bí wọn ti wà lórí omi; bayĩ sì ni á ngbé wọ́n síwájú níwájú afẹ́fẹ́. Wọ́n sì kọ orin ìyìn sí Olúwa; bẹ̃ni, arákùnrin Járẹ́dì sì kọ orin ìyìn sí Olúwa, ó sì dupẹ, o sì yìn Olúwa ní gbogbo ọjọ́; àti nígbati alẹ́ lẹ́, wọn kò ṣíwọ́ láti yìn Olúwa. Bayĩ sì ni a gbé wọn lọ síwájú; tí kò sì sí ohun abàmì inú omi kan ti ó lè dá wọn dúró, tàbí erinmi tí ó lè pa wọ́n lára; wọ́n sì ní ìmọ́lẹ̀ títí, bóyá wọ́n wà ní orí omi ni tàbí ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Báyĩ sí ni a gbé wọn lọ síwájú, fún oji le lọ̣́dunrun ọjọ́ ó lé mẹ́rin lórí omi nã. Wọn sì gúnlẹ̀ ní èbúté ilẹ̀-ìlérí nã. Nígbàtí wọ́n sì ti fi ẹsẹ̀ wọn lé èbúté ilẹ̀-ìlérí nã wọn tẹ̀ orí wọn bá lórí ilẹ̀ nã, wọn sì rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ níwájú Olúwa, wọ́n sì sọkún fún ayọ̀ níwájú Olúwa, nitori ọ̀pọ̀ ìrọ́nú ãnú rẹ lórí wọn. Ó sì ṣe tí wọn jáde lọ sí orí ilẹ̀ nã, wọn sì bẹ̀rẹ̀sí dáko. Járẹ́dì sì ní àwọn ọmọkùnrin mẹ́rin; a sì npè wọ́n ní Jákọ́mù, àti Gílgà, àti Máhà, àti Òríhà. Arákùnrin Járẹ́dì nã sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Àwọn ọrẹ Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ ènìyàn méjìlélógún; àwọn nã sì bí àwọn ọmọkúnrin àti ọmọbìrín kí wọn ó tó dé inú ilẹ̀-ìléri; àti nítori èyí wọ́n bẹ̀rẹ̀sí pọ̀sĩ. A sì kọ́ wọn láti máa rìn nínú ìrẹ̀lẹ ọkàn níwájú Olúwa; a sì kọ́ wọn láti òkè ọrun wá. O sì ṣe tí wọn bẹ̀rẹ̀sí tàn kálẹ̀ lórí ilẹ̀ nã, wọn sì nbísĩ, wọn sì ndáko lórí ilẹ̀ nã; wọn sì ndi alágbára nínú ilẹ̀ nã. Arákùnrin Járẹ́dì sì bẹ̀rẹ̀sí darúgbó, ó sì rí i pé òun fẹ́rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà-òkú; nítorí eyi ó wí fún Járẹ́dì pé: Jẹ́ kí àwa ó kó àwọn ènìyàn wa jọ kí àwa ó kà iye wọn, kí àwa lè mọ̀ láti ọwọ́ wọn ohun tí wọn fẹ kí àwa ó ṣe fún wọn kí a tó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà-òkú wa. Bẹ̃ gẹ́gẹ́ ní wọ́n sì kó àwọn ènìyàn nã jọ. Nísisìyí iye àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin Járẹ́dì jẹ́ ènìyàn méjìlélógún; àti iye àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Járẹ́dì jẹ́ méjìla, òun sì ní ọmọkùnrin mẹ́rin. O sì ṣe tí wọn kà iye àwọn ènìyàn wọ́n; àti nígbàtí wọn ti kà wọ́n tán, wọn bí wọ́n ni àwọn ohun tí wọn fẹ́ kí wọn ó ṣe ki wọn ó tó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ísà-òkú wọn. O sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã fẹ́ kí wọn ó fi òróró yàn ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin wọn láti jẹ́ ọba lé wọn lórí. Àti nísisìyí, èyí jẹ́ ohun tí ó bà wọ́n nínújẹ́. Arákùnrin Járẹ́dì sì wí fún wọn pé: Dájúdájú eleyĩ yíò já sí mímúni ní ìgbèkùn. Sùgbọ́n Járẹ́dì wí fún arákùnrin rẹ̀ pé: Jẹ́ kí wọn ó ní ọba. Nítorínã ó sì wí fún wọn pé: Ẹ yàn láti inú àwọn ọmọkùnrin wa láti jẹ́ ọba, àní ẹniti ẹ̀yín bá fẹ́. O sì ṣe tí wọ́n yàn àní àkọ́bí arákùnrin Járẹ́dì; orúkọ rẹ̀ sì ni Págágì. O sì ṣe tí ó kọ̀ tí kò sì gbà láti jẹ́ ọba wọn. Àwọn ènìyàn nã sì fẹ́ kí bàbá rẹ̀ ó rọ̀ ọ́, ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ kọ̀; ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó máṣe rọ̀ ẹnikẹ́ni láti jẹ́ ọba wọn. O sì ṣe tí wọn yàn gbogbo àwọn arákùnrin Págágì, ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀. O sì ṣe tí kò sí èyíkéyi nínú àwọn ọmọkùnrin Járẹ́dì, àní nínú gbogbo wọn, bíkòṣe ọ̀kan, a sì fi àmì òróró yàn Òríhà láti jẹ́ ọba lórí àwọn ènìyàn nã. O sì bẹ̀rẹ̀sí jọba, àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí ní ìlọsíwájú; wọn sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀ ènìyàn. Ó sì ṣe tí Járẹ́dì kú, àti arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú. O sì ṣe ti Oríhà sì nrin nínú ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn níwájú Olúwa, ó sì ranti àwọn ohun nla tí Olúwa ti ṣe fún bàbá rẹ̀, ó sì kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú nípa àwọn ohun nlá tí Olúwa ti ṣe fún àwọn bàbá wọn. 7 Òríhà jọba nínú òdodo—Nínú ìfipágbà ìjọba àti ìjà, a gbé àwọn orogún ìjọba ti Ṣúlè, àti ti Kóhọ̀ kalẹ̀—Àwọn wòlĩ dá àwọn ènìyàn nã lẹ́bí fun ìwà búburú àti ìwà ìbọ̀rìṣà wọn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà. Ósì ṣe tí Òríhà sì ṣe ìdájọ́ lórí ilẹ̀ nã nínú òdodo ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, ẹ̀nítí ọjọ́ ayé rẹ̀ pọ̀ púpọ̀. Ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin; bẹ̃ni, ó bí mọ̀kànlélọ́gbọ̀n, nínú èyítí àwọn mẹ́tàlélógún jẹ́ ọmọkùnrin. Ó sì ṣe tí ó bí Kíbù pẹ̀lú nínú ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ó sì ṣe tí Kíbù jọba ní ìrọ́pọ̀ rẹ̀; Kíbù sì bí Kóríhọ̀. Nígbàtí Kóríhọ̀ sì jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélọ́gbòn, ó ṣọ̀tẹ̀sí bàbá rẹ̀, ó sì kọjá lọ ó sì ngbé inú ilẹ̀ Néhọ́rì; ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin, wọ́n sì di arẹwà ènìyàn púpọ̀, nítorí eyi Kóríhọ̀ fà ènìyàn púpọ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀. Nígbàtí ó sì ti kó ẹgbẹ́ ogun kán jọ́ ó gòké wá sínú ílẹ̀ Mórọ̀n níbití ọba ngbé, ó sì múu ní ìgbèkùn, èyítí ó mú ọ̀rọ̀ arákùnrin Járẹ́dì sẹ pé a ó mú wọn ní ìgbèkùn. Nísisìyí ilẹ̀ Mórọ̀n, níbití ọba ngbé, súnmọ́ ilẹ̀ tí àwọn ará Nífáì ńpè ní Ibi-Ahoro. Ó sì ṣe tí Kíbù ngbé inú ìgbèkùn, àti àwọn ènìyàn rẹ̀ lábẹ́ Kóríhọ̀ ọmọ rẹ̀, titi ó fi di arúgbó púpọ̀púpọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃ Kíbù bí Ṣúlè nínú ọ́jọ́ ogbó rẹ̀, nígbàtí ó wà nínú ìgbekùn síbẹ̀. Ó s ì ṣe t í Ṣúlè bínú s í arákùnrin rẹ; Ṣúlè sì nlágbára sí i, ó sì di alágbára níti ipá ènìyàn; ó sì lágbára pẹ̀lú níti ìdájọ́. Nítorí èyí, ó lọ sínú òké Efráímù, ó sì yọ́ irin tútù jáde láti inú oke nã, ó sì rọ àwọn idà fún àwọn tí ó ti fà lọ pẹ̀lú rẹ́; nígbàtí ó sí ti dì wọ́n ní ìhámọ́ra pẹ̀lú àwọn idà, ó padà sí ìlú-ńlá Néhórì, ó sí dojú ogun kọ arákùnrin rẹ̀ Kóríhọ̀, nípa èyítí ó gbà ìjọba nã o sì dáa padà fún bàbá rẹ̀ Kíbù. Àti nísisìyí nítorí ohun tí Ṣúlè ti ṣe, bàbá rẹ̀ fi ìjọba nã fún un; nítori èyí ó bẹ̀rẹ̀sí jọba ní ìrọ́pò bàbá rẹ̀. O sì ṣe tí ó ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú òdodo; ó sì tàn ìjọba rẹ̀ ká gbogbo òrí ilẹ̀ nã, nítorítí àwọn ènìyàn nã ti pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. O sì ṣe tí Ṣúlè pẹ̀lú bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin púpọ̀. Kóríhọ̀ sì ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ohun ibi tí ó ti ṣe; nítorí eyi Ṣúlè fún un ní agbára nínú ìjọba rẹ̀. Ó sì ṣe tí Kóríhọ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Ẹnìkan tí orukọ rẹ í ṣe Nóà sì wà nínú àwọn ọmọkùnrin Kóríhọ̀. Ó sì se tí Nóà ṣọ̀tẹ̀ sí Ṣúlè, ọba, àti sí bàbá rẹ̀ Kóríhọ̀, ó sì fà Kohọ̀ arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn nã. O sì dojú ogun kọ Ṣúlè, ọba, nínú èyítí ó sì gbà ilẹ̀ ìní akọ́kọ́ wọn; ó sì di ọba lórí ílẹ tí ó wà ní apá ibẹ̀. O sì ṣe tí ó tún dojú ogun kọ Ṣúlè, ọba; ó sì mú Ṣúlè, ọba, ó sì gbé e lọ ní ìgbèkùn sínú Mórọ̀n. Ó sì ṣe bí ó ti múra tán láti pa á, àwọn ọmọ Ṣúlè yọ́kẹ́lẹ́ wọ̀ ínú ilé Nóà ní òru wọ́n sì pa, wọ́n sì fọ́ ilẹ̀kùn tũbú nã wọ́n sì mú bàbà wọn jáde, wọ́n sì dáa padà sórí ìtẹ́ rẹ̀ nínú ìjọba ara rẹ̀. Nítorí èyí, ọmọkùnrin Nóà sì ńṣe ìjọba rẹ̀ dípò rẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọn kò ri agbára gbà lé Ṣúlè ọba lórí, àwọn ènìyàn tí ó sì wà lábẹ́ ìjọba Ṣúlè ọba sì ni ìlọsíwájú púpọ̀púpọ̀ wọ́n sì di alágbára ènìyàn. Ìpínyà sì wà ní orílẹ̀èdè nã; ìjọba méjì ní ó sì wà, ìjọba Ṣúlè, àti ìjọba Kohọ̀, ọmọ Nóà. Kohọ̀, ọmọ Nóà sì mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó dojú ogun kọ Ṣúlè, nínú èyítí Ṣúlè borí wọn tí ó si pa Kohọ̀. Àti nísisìyí Kohọ̀ ní ọmọkunrin kan tí a npè ní Nímrọ́dù; Nímrọ́dù sì fi ìjọba Kóhọ̀ lélẹ̀ fún Ṣúlè, ó sì rí ojú rere Ṣúlè; nítorí eyi Ṣúlè sì ńfí àwọn ohun púpọ̀ jínkí rẹ̀, ó sì nṣe ìjọba Ṣúlè gẹ́gẹ́bí ó ti wũ. Àti pẹ̀lú nínú ìjọba Ṣúlè àwọn wòlĩ sì dé sí ãrín àwọn ènìyàn nã, awọn ẹni tí a rán láti ọ̀dọ̀ Olúwa, tí wọ́n sì ńsọ àsọtẹ́lẹ́ pé ìwà búburú àti ìwà ìbọ̀rìṣà àwọn ènìyàn nã ní ó nmú ègún wa sí orí ilẹ̀ nã, pé a ó sì pa wọ́n run bí wọn kò bà ronúpìwàdà. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyan nã sì ńkẹ́gàn àwọn wòlĩ nã, tí wọ́n sì ńfi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà. Ó sì ṣe tí ọba Ṣúlè sì ṣe ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí nkẹ́gàn àwọn wòlĩ nã. O sì ṣe òfin kan jákè-jádò ilẹ̀ nã, èyítí ó fún àwọn wòlĩ nã ní agbára láti lè lọ sí ibikíbi tí ó bá wù wọ́n; nítorínã a sì mú àwọn ènìyàn nã wá sí ìrònúpìwàdà. Àti nítorípé àwọn ènìyàn nã ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn àìṣedẽdé àti àwọn ìwà ìbọ̀rìṣà wọn Olúwa sì dá wọn sí, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀sí ní ìlọsíwájú nínú ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí Ṣúlè bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Àwọn ogun kò sì sí mọ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé Ṣúlè; ó sì rántí àwọn ohun nlá tí Olúwa tí ṣe fún àwọn baba rẹ̀ ní mímú wọn kọjá lórí òkun ńlá sínú ilẹ̀ ìlérí;nítorí eyi ó ṣe ìdájọ́ nínú òdodo ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 8 Ijà àti asọ̀ wà lórí ilẹ̀ nã—Ákíṣì kó àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn kàn jọ ti wọn darapọ̀mọ́ra pẹ̀lú ìbúra láti pa ọba—Àwọn ẹgbẹ òkùnkùn jẹ́ ti èṣù wọn a sì máa jẹ́ ki orílẹ̀ èdè ó parun—Àwọn Kèfèrí òde oni gbà ìkìlọ̀ lórí ẹgbẹ òkùnkùn tí yíò lépa láti bì òmìnira ilẹ̀ gbogbo, orílẹ̀-èdè, àti àwọn ìlú ṣubú. Ó sì ṣe tí ó bí Ómérì, Ómérì sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀. Ómérì sì bí Járẹ́dì; Járẹ́dì sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Járẹ́dì sì ṣọ̀tẹ̀ sí bàbá rẹ̀, ó sì wá ó sì ngbé inú ilẹ̀ Hẹ́tì. Ó sì ṣe tí ó ntàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, nitori ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀, títí ó fi gbà ìdajì ìjọba nã. Nígbàtí o sì ti gbà ìdajì ijọba nã ó dojú ogun kọ bàbá rẹ̀, ó sì gbé bàbá rẹ̀ lọ ní ìgbèkùn, ó sì jẹ́ ki o sìn nínú oko ẹrú; Àti nísisìyí, ní gbogbo ọjọ́ tí Ómérì fi jọba ó wà nínú ìgbèkùn ní ilàjì ọjọ́ ayé rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin, nínú wọn ni Ésrómù àti Kóríántúmúrì gbé wà; Wọ́n sì bínú gidigidi nítorí àwọn ìṣe Járẹ́dì arákùnrin wọn, tóbẹ̃ tí wọ́n kó ẹgbẹ́ ogun jọ tí wọ́n sì dojú ogun kọ Járẹ́dì. Ó sì ṣe tí wọn dojú ogun kọ ọ́ ní òru. Ó sì ṣe nígbàtí wọn ti pa ẹgbẹ́ omọ ọgun Járẹ́dì wọn ṣetán láti pa òun nã; ó sì ṣìpẹ̀ sí wọn kí wọn ó máṣe pa òun, pé òun yíò fi ijọba nã lé bàbá òun lọ́wọ́. Ó sì ṣe tí wọ́n jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ sílẹ̀ fún un. Àti nísisìyí ìrora ọkàn nla sì bá Járẹ́dì nítorítí ó sọ ìjọba nã nù, nítorítí ó ti gbé ọkàn rẹ̀ lérí ìjọba nã àti lérí ògo ayé. Nísisìyí ọmọbìnrin Járẹ́dì jẹ́ ọlọgbọ́n àrekérekè ènìyàn, nígbàtí ó sì rí ìrora ọkàn bàbá rẹ̀, o ronú láti pa ète ọ̀nà tí òun yíò fi dá ìjọ́bá padà fún bàbá òun. Nísisìyí ọmọbìnrin Járẹ́dì rẹwà púpọ̀. Ó sì ṣe tí ó bá bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì wí fún un pé: Kíni ìdí ti bàbá mi fi ní ìrora ọkàn tó báyĩ? Njẹ́ òun kò ha kà àkọsílẹ̀ nnì èyítí àwọn bàbá wa mú kọjá lórí òkun nlá nnì bí? Kíyèsĩ, njẹ́ kò ha sí àkọsílẹ̀ nípa àwọn ará ìgbà àtijọ́, pé nípa àwọn ìlànà òkùnkùn, wọn wọ́n ngbà àwọn ìjọba àti ògo nlá? Àti nísisìyí, nítorínã, kí bàbá mi ó ránṣẹ́ pè Ákíṣì, ọmọ Kímnórì; sì kíyèsĩ, mo lẹ́wà, èmi yíò sì jó níwájú rẹ̀, èmi yíò sì mú inú rẹ̀ dùn, tí yíò fẹ́ láti fi mi ṣe aya; nítorí eyi bí ó bá bí ọ́ pé kí o fi mí fún oun ní aya, nígbànã ni ìwọ yíò wípé: Èmi yíò fi í fún ọ bí ìwọ ó bá mú orí bàbá mi ọba, wá fún mi. Àti nísisìyí Ómérì sì jẹ́ òrẹ́ sí Ákíṣì; nítorí èyí, nígbàtí Járẹ́dì ránṣẹ́ pè Ákíṣì, ọmọbìnrin Járẹ́dì jó níwájú rẹ̀ tí ó sì mú inú rẹ̀ dùn, tóbẹ̃ tí ó fẹ́ ẹ fún aya. Ó sì ṣe tí ó wí fún Járẹ́dì pé: Fi í fún mi fún aya. Járẹ́dì sì wí fún un pe: Èmi yíò fi í fún ọ, bí ìwọ ó bá mú ori baba mi, ọba, wá fún mi. O sì ṣe tí Ákíṣì kó gbógbo àwọn ará-ilé rẹ̀ jọ sínú ilé Járẹ́dì, ó sì wí fún wọn pé: Njẹ́ ẹ̀yin ha lè búra fún mi pé ẹ̀yin yíò ṣeòtítọ́ pẹ̀lú mi nínú ohun èyítí èmi fẹ kí ẹ̀yin ó ṣe? Ó sì ṣe tí gbogbo wọn búra fún un, ní ti Ọlọ́run ọ̀run, àti pẹ̀lú ní ti àwọn ọ̀run, àti pẹ̀lú ní ti ayé, àti ní ti orí ara wọn, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyítí ó yàtọ̀ sí ìrànlọ́wọ́ ti Ákíṣì fẹ́ yíò pàdánù orí ara rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bà sì fí ohunkóhun tí Ákíṣì yíò sọ di mímọ̀ fún wọn hàn, ẹni nã yíò pàdánù ẹ̀mí rẹ̀. Ó sì ṣe ti wọn fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú Ákíṣì. Ákíṣì sì ṣe ìbúra nã pẹ̀lú wọn èyítí àwọn ará ìgbà àtijọ́ tí nwá agbára a máa ṣe, èyítí a ti gbé fún wọn láti ọwọ́ Káìnì, ẹnití í ṣe apànìyàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Agbára èṣù ní ó sì gbe wọn ró láti mã ṣe ìbúra yĩ sí àwọn ènìyàn, láti fi wọn sínú òkùnkùn, láti ràn àwọn tí nwá agbára lọ́wọ́ láti ní agbára, àti láti pànìyàn, àti láti kógun, àti láti purọ́, àti láti hù onírúurú ìwà búburú àti ìwà àgbèrè. Ọmọbìnrin Járẹ́dì sì ni ẹnití ó fi í sínú ọkàn rẹ̀ láti gbé àwọn ohun àtijọ́ wọ̀nyí yẹ̀ wò; Járẹ́dì sì fi í sínú ọkàn Ákíṣì; nítorí eyi, Ákíṣì ṣe wọn fún àwọn ìbátan àti àwọn òrẹ́ rẹ̀, tí ó sì darí wọn lọ nípa àwọn ìlérí dídùn láti ṣe ohunkóhun tí óun bá fẹ́ kí wọn ó ṣe. O sì ṣe tí wọn dá ẹgbẹ́ òkùnkùn kan sílẹ̀, àní bí ti àwọn ará àtijọ́; ẹgbẹ́ èyítí o rínilára àti tí ó níkà jùlọ, ni ojú Ọlọ́run; Nítorítí Olúwa kì í ṣíṣẹ́ nínú àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn, bẹ̃ni kò sì fẹ́ kí àwọn ènìyàn ó tàjẹ̀sílẹ̀, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo ni ó ti kã-lẽwọ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ènìyàn. Àti nísisìyí emí, Mórónì, kò kọ nípa irú àwọn ìbúra àti àwọn ẹgbẹ́ wọn, nítorítí a ti sọ ọ́ di mímọ̀ fún mi pé gbogbo ènìyàn ni ó ní wọn, àti pé gbogbo àwọn ará Lámánì ni ó ní wọn. Wọ́n sì ti fa ìparun àwọn ènìyàn yĩ tí èmí nsọ̀rọ̀ nipa wọn nísisìyí, àti ìparun àwọn ènìyàn Nífáì. Orílẹ̀èdè èyíówù tí ó bà sì tì ìrú àwọn egbẹ́ òkùnkùn bẹ̃ lẹ́hìn, láti ní agbára àti èrè, títí wọn yíò fi tàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè nã, ẹ́ kíyèsĩ, á ó pa wọ́n run; nítorítí Olúwa kò ní gbà kí ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, ti wọn yíò ta silẹ, máa kígbe pè é láti inú ilẹ̀ wá fún ìgbẹ̀san lórí wọn, àti síbẹ̀síbẹ̀ kí ó má gbẹ̀san fún wọn. Nítorí èyí, A! ẹ̀yín Kèfèrí, ó jẹ ohun ọgbọ́n nínú Ọlọ́run kí a fi àwọn ohun wọ̀nyí hàn yín, pé nípasẹ̀ wọn ẹ̀yin ó lè ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ́ má sì jẹ́ kí àwọn ẹgbẹ́ apànìyàn wọ̀nyí ó bò yín mọ́lẹ̀, èyítí wọ́n kójọ láti ni agbára àti èrè—àti iṣẹ́ nã, bẹ̃ni, àní kí iṣẹ́ ìparun nã sì wà sí órí yín, bẹ̃ni, àní idà àìṣègbè ti Ọlọ́run Ayérayé yíò sì ṣubú lù yín, sí ìṣúbu àti ìparun yín bí ẹyin bá gbà àwọn ohun wọ̀nyí lãyè. Nítorí èyí, Olúwa pa a láṣẹ fún yín, nígbàtí ẹ̀yin ó bá ri àwọn ohun wọ̀nyí tí ó dé sí ãrín yín pé kí ẹ̀yin ó tají sí ipò búburú tí ẹ̀yin wa nínú rẹ̀, nítorí ẹgbẹ́ òkùnkùn yĩ èyítí yíò wà ní ãrín yín; tabi ègbé ni fún un, nitorí ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n ti pa; nítorítí wọ́n nkigbe láti inú erùpẹ̀ wáfún ẹ̀san lórí rẹ̀, àti pẹ̀lú lórí àwọn tí ó dáa sílẹ̀. Nítoriti yíò sì ṣe tí ẹnikẹ́ni tí ó bá dá a silẹ̀ nlépa láti gbé òmìnira ilẹ̀ gbogbo, orílẹ̀-èdè, àti àwọn ìlú ṣubú; ó sì nmú ìparun bá ènìyàn gbogbo, nítorítí èṣù ní ó dáa sílẹ̀, ẹnití í ṣe bàbá irọ́ gbogbo; àní òpùrọ́ nnì ẹnití ó tàn àwọn òbí wa àkọ́kọ́, bẹ̃ni, àní òpùrọ́ kannã ẹnití ó mú kí àwọn ènìyàn ó ṣe ìpànìyàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá; ẹnití ó ti sé ọkàn àwọn ènìyàn le tí wọ́n sì ti pa àwọn wòlĩ, tí wọn sì sọ wọ́n lókùta, tí wọ́n sì sọ wọ́n sóde láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Nítorí èyí, emí, Mórónì, ni Olúwa pàṣẹ fún láti kọ àwọn ohun wọ̀nyí kí a lè mú ohun búburú kúrò, àti kí àkókò nã ó lè dé tí Sátánì kì yíò ní agbára mọ́ lórí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn, ṣùgbọ́n pé a ó yí wọn lọ́kàn padà láti ṣe réré títí, kí wọn ó lè wá sí ọ̀dọ̀ orísun gbogbo òdodo kí a sì gbà wọn là. 9 Ijọba nti ọwọ́ ẹnìkan bọ́ sí ọwọ ẹlòmíràn ní tí àjogúnbá, rìkíṣí, àti ìpànìyàn—Émérì rí Ọmọ Òdodo nnì—Àwọn wòlĩ púpọ̀ nkígbe ìrònúpìwàdà—Ìyàn kan àti àwọn ejò oloro bá àwọn ènìyàn nã jà. Àti nísisìyí èmi, Mórónì, tẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn àkọsílẹ̀ mí. Nítorínã, ẹ kíyèsĩ, ó sì ṣe tí ó jẹ́ wípé nitori àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn Ákíṣì áti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ẹ kíyèsĩ, wọ́n sì gbé ìjọba Ómérì ṣubú. Bíólitẹ̀ríbẹ̃, Olúwa ṣãnú fún Ómérì, àti fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrín rẹ̀ tí kò wá ìparun rẹ̀. Ọlọ́run sì kìlọ̀ fun Ómérì lójú àlá pé kí ó jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã; nítorí èyí Ómérì jáde kuro nínú ilẹ̀ nã pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, wọ́n sì rìn ìrìn àjò fun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, wọ́n sì dé sí ibi òkè Ṣímù, wọ́n sì kọjá rẹ̀, wọ́n sì dé ibiti a ti pa àwọn ara Nífáì run, wọ́n sì lọ láti íbẹ̀ sí apá ìlà-oòrùn, wọ́n sì dé ibì kan tí wọ́n npè ní Ablómù, lẹba etí bèbè òkun, níbẹ̀ ni ó sì pàgọ́ rẹ̀ sí, àti pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, àti gbogbo agbo-ilé rẹ̀, àfi Járẹ́dì àti ìdílé rẹ̀. O sì ṣe tí a fi àmì òróró yàn Járẹ́dì ní ọ́ba lórí àwọn ènìyàn nã, nípa ọ̀nà ìwà búburú; ó sì fún Ákíṣì ní ọmọ rẹ̀ obìnrin láti fi ṣe aya. O sì ṣe tí Ákíṣì lépa ẹ̀mí bàbá ìyàwó rẹ̀; ó sì bẽrè ìrànlọ́wọ́ àwọn tí ó ti mú kí wọn ó búra pẹ̀lú ìbúra àwọn ará àtijọ́, wọn sì bẹ́ orí bàbá ìyàwò rẹ̀, bí ó ti jóko lórí ìtẹ́ rẹ̀, bí ó tí ngbọ ti àwọn ènìyàn rẹ̀. Nítorítí ìtànkálẹ̀ ẹgbẹ́ òkùnkùn tí ó ní ìkà yì í pọ̀ púpọ̀ tí ó ti mú ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn nã díbàjẹ́; nítorínã wọn pa Járẹ́dì lórí ìtẹ́ rẹ̀, Ákíṣì sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀. Ó sì ṣe tí Ákíṣì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìlara ọmọkùnrin rẹ̀, nitorinã ó tĩ mọ́ inú tũbú, ó sì nfún un ni onjẹ díẹ̀ tabi kí ó ma fún un rárá titi ó fi kú. Àti nísisìyí arákùnrin ẹnití ó kú, (orúkọ rẹ̀ sì ni Nímrà) bínú sì bàbá rẹ̀ nítorí ohun tí bàbá rẹ ti ṣe sí arákùnrin rẹ̀. O sì ṣe tí Nímrà kó àwọn ọkùnrin díẹ̀ jọ, tí wọn sì sá kúrò ní ilẹ̀ nã, wọ́n sì de ọ̀dọ̀ Ómérì wọ́n sì ngbé pẹ̀lú rẹ̀. O sì ṣe tí Ákíṣì bí àwọn ọmọkùnrin míràn, wọ́n sì rí ojú rere àwọn èniyàn nã, bí ó tilẹ̀ rí bẹ̃ wọ́n ti pinnu pẹ̀lú rẹ̀ láti ṣe onírúurú àìṣedẽdé ní ìbámu pẹ̀lú èyítí ó fẹ́. Nísisìyí àwọn ènìyàn Ákíṣì fẹ́ èrè, àní bí Ákíṣì ti fẹ agbara; nítori èyí, àwọn ọmọ Ákíṣì fí owó fún wọn, nípa èyítí wọn fa èyítí ó pọ̀ jù nínú àwọn ènìyàn nã sí ọ̀dọ̀ wọn. Ogún kan sì bẹ́ sílẹ̀ lãrín àwọn ọ́mọ Ákíṣì àti Ákíṣì, tí ó pẹ́ fún ìwọ̀n ọdún púpọ̀, bẹ̃ni, tí ó fẹrẹ pa gbogbo àwọn ènìyàn inú ìjọba nã run tán, bẹ̃ni, àní gbogbo wọn, afi àwọn ọgbọ̀n ènìyàn, àti àwọn tí ó sa pẹ̀lú ìdílé Ómérì. Nítorí eyi, wọ́n sì tún dá Ómérì padà sí órí ilẹ̀ ìní rẹ̀. O sì ṣe tí Ómérì bẹ̀rẹ̀sí darúgbó; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ó bí Émérì, ó sì fi àmì òróró yàn Émérì láti jọba ní ìrọ́pò rẹ̀. Lẹ́hìn tí ó sì ti fí àmì òróró yàn Émérì láti jọba ó rí àlãfíà nínú ilẹ̀ nã fún ìwọ̀n ọdún méjì, ó sì kú, lẹ́hìn tí ó ti rí òpọ̀lọpọ̀ ọjọ, èyítí ó kún fún ìrora-ọkàn. O sì ṣe tí Émérì jọba ní ìrọpò rẹ̀, ó sì rìn nínú ipaṣẹ̀ bàbá rẹ̀. Olúwa sì tún bẹ̀rẹ̀sí mú ègun kúrò lórí ilẹ̀ nã, ìdílé Émérì sì ní ìlọsíwájú tí ó pọ̀ púpọ̀ ní abẹ ìjọba Émérì; àti nínú ìwọ̀n ọdun méjìlélọ́gọ́ta ní wọ́n sì ti di álágbára púpọ̀, tóbẹ̃ tí wọ́n di ọlọ́rọ̀ púpọ̀— Tí wọn sì ni onírúurú èso, àti ti ọkà, àti tí àwọn aṣọ ṣẹ́dà, àti ti àwọn aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, àti tí wúrà, àti tí fàdákà, àti tí àwọn ohun oníyebíye; Àti pẹ̀lú àwọn onírúurú màlũ, àti àwọn abo màlũ, àti ti àgùtàn, àti ti ẹlẹ́dè, àti ti ewúrẹ́, àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú àwọn ẹranko miràn tí ó wúlò fún onjẹ ènìyàn. Wọn sì ní àwọn ẹṣin pẹ̀lú, àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn erin sì wà níbẹ̀ àti àwọn kúrílọ́mù àti àwọn kúmọ́mù; tí gbogbo wọn wúlò fún ènìyàn, àti pãpã àwọn erin àti àwọn kúrílọ́mù àti àwọn kúmọ́mù. Bayĩ sì ni Olúwa dà ìbùkún rẹ̀ sí ori ilẹ̀ yí, èyítí ó jẹ́ àsàyàn ju gbogbo ilẹ míràn lọ; ó sì pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí yíò bá ní ilẹ̀ nã ní ìní níláti ní i sí Olúwa, tàbí kí a pa wọ́n run nígbàtí wọn bá ti gbó nínú àìṣedẽdé; pé ni orí irú èyí nì, ni Olúwa wí: Èmi yíò da ẹ̀kún ìbínú mi lé. Émérì sì ṣe ìdájọ́ nínú òdodo ní gbogbo ayé rẹ̀, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin púpọ̀; ó sì bí Koríántúmù, ó sì fi àmì òróró yàn Koríántúmù láti jọba ní ìrọ́pò rẹ̀. Lẹ́hìn tí ó sì ti fi àmì òróró yàn Koríántúmù láti jọba ní ìrọ́pọ̀ rẹ̀ ó gbé fún ọdún mẹ́rin, ó sì rí àlãfíà nínú ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, àní ó sì ri Ọmọ Òdodo nã, ó sì yọ̀ ó sì ṣògo nínú ọjọ ayé rẹ̀; ó sì kú ní àlãfíà. Ó sì ṣe tí Koríántúmù sì nrìn nínú ipàsẹ̀ bàbá rẹ̀, ó sì kọ́ àwọn ilu nla nla, ó sì nfí èyítí ó dára fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní gbogbo ọjọ ayé rẹ̀. Ó sì ṣe tí kò ní àwọn ọmọ àní títí ó fi darúgbó púpọ̀púpọ̀. O sì ṣe tí aya rẹ̀ kú, nígbàtí ó pé ẹni ọdún méjì le lọ́gọ́run. O sì ṣe ti Koríántúmù gbé ọmọdebinrin kan ní ìyàwó, nínú ọjọ́ ogbó rẹ, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin; nítorí eyi ó gbé ayé títí ó fi pé ẹni ọdùn méjìlélógóje. O sì ṣe tí ó bí Kọ́mù, Kọ́mù sì jọba ní írọ́pò rẹ̀; ó jọba fún ọdun mọ́kàndínlógojì, ó sì bí Hẹ́tì; ó sí bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin míràn pẹ̀lú. Àwọn ènìyàn nã sì ti tún tàn ká gbogbo orí ilẹ̀ nã, ìwà búburú tí ó pọ̀ púpọ̀ sì tún bẹ̀rẹ̀sí wà lórí ilẹ̀ nã, Hẹ́tì sì tún bẹ̀rẹ̀sí gbà àwọn ète okùnkùn tí ìgbà àtijọ́, láti pa bàbá rẹ̀ run. O sì ṣe tí ó sì rọ̀ bàbá rẹ̀ lórí oyè, nítorítí ó pa á pẹ̀lú idà ara rẹ̀; ó sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀. Àwọn wòlĩ sì tún wá sí ilẹ̀ nã, tí wọn si nkigbe ìrònúpìwàdà sí wọn—pé wọn gbọdọ̀ tún ọ̀nà Olúwa ṣe tàbí kí ègún ó wá sí órí ilẹ̀ nã; àní ìyàn nla yíò wà, nínú èyítí a ò pà wọ́n run bí wọn kò bá ronúpìwàdà. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn nã kò gbà ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ nã gbọ́, ṣùgbọ́n, wọ́n le wọ́n jade; wọ́n sì jù àwọn míràn nínú wọn sínú kòtò tí wọ́n fi wọn sílẹ̀ láti ṣègbé. Ó sì ṣe tí wọ́n ṣe ohun gbogbo ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ọba, Hẹ́tì. O sì ṣe tí ìyàn nlá kan mú lórí ilẹ̀ nã, àwọn olùgbé inú ilẹ̀ nã sì bẹ̀rẹ̀sí parun ní kíakía nítorí òjò kò rọ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn ejò olóró sì jáde wá pẹ̀lú lórí ilẹ̀ nã, wọ́n sì bù ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ṣán. O sì ṣe tí àwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn bẹ̀rẹ̀sí sálọ kúrò níwájú àwọn ejò olóró nã, lọ sí apá ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù, èyítí àwọn ará Nífáì npè ní Sarahẹ́múlà. O sì ṣe tí ó pọ̀ nínú wọn tí ó ṣègbé lọ́nà; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn kan wà tí wọ́n salọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù. O sì ṣe tí Olúwa mú kí àwọn ejò nã ó má lé wọn mọ́, ṣùgbọ́n kí wọn dí ọna kí àwọn ènìyàn nã ó má lè kọjá, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìdanwò láti kọjá lè ṣubú nípasẹ̀ àwọn ejò olóró nã. O si ṣe tí àwọn ènìyàn nã sì ntẹ̀lé ipa ọ̀nà àwọn ẹranko wọn, wọ́n sì njẹ okú àwọn tí ó ṣègbé lọ́nà, titi wọn fi jẹ gbogbo wọn tán. Nísisìyí nígbàtí àwọn ènìyàn nã rĩ pé wọn yíò ṣegbé wọn bẹ̀rẹ̀sí ronúpìwàdà kúrò nínú àìṣedẽdé wọn, wọ́n sì ké pè Olúwa. Ó sì ṣe nígbàtí wọn ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ tó níwájú Olúwa ó sì rán òjò sí órí ilẹ̀ ayé; àwọn ènìyàn nã sì tún bẹ̀rẹ̀sí ní ókun lára, èso sì bẹ̀rẹ̀sí wà ní àwọn orílẹ̀-èdè apá àríwá, àti nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o wà ní àyíká. Olúwa sì fi agbara rẹ̀ hàn sí wọn ni ti dídá wọn sí kúrò lọ́wọ́ ìyàn. 10 Ọba kan rọ́pò òmíràn—Àwọn kan nínú àwọn ọba nã jẹ olódodo; àwọn míràn jẹ oníwá búburú—Nígbàtí ìwà òdódo bá borí, Olúwa yíò bùkún yíò sì mú àwọn ènìyàn ṣe rere. O sì ṣe tí Ṣẹ́sì tí ó jẹ ìran Hẹ́tì—nítorítí Hẹ́tí ti ṣègbé nínú ìyàn, àti gbogbo ilé rẹ̀, àfi Ṣẹ́sì—nítoríeyi, Ṣẹ́sì bẹ̀rẹ̀sí mú àwọn ènìyàn nã lọ́kàn le. Ó sì ṣe tí Ṣẹ́sì rántí ìparun àwọn bàbá rẹ̀, ó sì kọ́ ijọba òdodo; nítorítí ó rántí ohun tí Olúwa ti ṣe ní mímú Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀ kọjá nínú òkun jíjìn nã; ó sì nrìn nínú ọ̀nà Olúwa; ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó dàgbà jù, tí orúkọ rẹ̀ í ṣe Ṣẹ́sì, sì ṣọ̀tẹ̀ sí i; bíótilẹ̀ríbẹ̃ a pa Ṣẹ́sì láti ọwọ ọlọ́ṣà kan, nitori ọrọ̀ púpọ̀ tí ó ní, èyítí ó sì mú kí àlãfíà ó tún padà bá bàbá rẹ̀. Ó sì ṣe tí bàbá rẹ̀ sì kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú nlá lórí ilẹ̀ nã, àwọn ènìyàn nã sì tún bẹ̀rẹ̀sí tàn ká lórí gbogbo ilẹ̀ nã. Ṣẹ́sì sì wà lãyè títí di ọjọ́ ogbó tí ó pẹ́ púpọ̀; ó sì bí Ríplákíṣì. O sì kú, Ríplákíṣì sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀. O sì ṣe tí Ríplákíṣì kò sì ṣe èyítí ó tọ́ ní ojú Olúwa, nítorití ó ní àwọn aya púpọ̀ àti àwọn àlè, ó sì nfún àwọn ènìyàn nã ní ohun tí ó ṣòró fún wọn láti ṣe; bẹ̃ni, ó mú wọn san owo ode tí ó pọ̀ púpọ̀; pẹ̀lú àwọn owo òde wọ̀nyí ni ó sì nkọ àwọn ilé nlá-nlá. Ó sì kọ́ ìtẹ́-ọba tí ó dára púpọ̀ fún ara rẹ̀; ó sì kọ àwọn tũbú púpọ̀, ẹnikẹ́ni tí kò bá sì san owó òde ní ó jù sínú tũbú; àti ẹnikẹ́ni tí kò bá lè san owó orí ní ó sì jù sínú tũbú, ó sì mú kí wọn ó máa ṣe lãlã títí fún ìtìlẹ́hìn wọn; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti ṣe lãlã ní ó mú kí wọn ó pa. Nítorí eyi ni ó fi rí gbogbo àwọn iṣẹ́ dáradára rẹ̀, àní àwọn wura rẹ̀ dáradára pàapã ní ó mú kí wọ́n ó tún dà nínú tũbú; àti gbogbo onírũrú iṣẹ́ ọwọ́ ni ó mú kí wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́ nínú túbú. Ó sì ṣe tí ó pọ́n àwọn ènìyàn nã lójú pẹ̀lú ìwà àgbèrè àti àwọn ohun ìríra. Àti nígbàtí ó sì ti jọba fún ìwọ̀n ọdun meji le logójì, àwọn ènìyan nã dìdé ní ìṣọ̀tẹ̀ sí i; ogun sì bẹ̀rẹ̀sí tún wà ní ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí wọ́n pa Ríplakíṣì, àwọn ìran rẹ̀ ní wọ́n sì lé jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã. O sì ṣe lẹ́hìn ìwọ̀n ọdún tí ó pọ̀, Moríántónì, (ẹnití ó jẹ ìran Ríplákíṣì) kó ẹgbẹ́ ọmọ ogún kàn jọ lára áwọn àṣátì ènìyàn, ó sì kọjá lọ ó sì gbé ogun kọlũ àwọn ènìyàn nã; ó sì gbà agbára lórí àwọn ìlú nlá púpọ̀; ogun nã sì dí èyití ó gbóná púpọ̀púpọ̀; ó sì wà fun ìwọ̀n ọdún tí ó pọ̀; ó sì gbà agbára lórí gbogbo ilẹ̀ nã, ó sì fí ara rẹ̀ múlẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọ́ba lórí gbogbo ilẹ̀ nã. Lẹ́hìn tí ó sì ti fí ẹsẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọba ó sì dẹ̀ àjàgà ọrùn àwọn ènìyàn nã, nípa èyítí ó rí ojú rere lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nã, wọ́n sì fi àmì òróró yàn án láti jẹ́ ọba wọn. O sì ṣe àìṣègbè si àwọn ènìyàn nã, láìṣe sí ara rẹ̀ nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà àgbèrè rẹ̀; nítorí eyi á ké e kúrò níwájú Olúwa. O sì ṣe tí Moriántónì kọ́ ìlú nlá tí ó pọ̀, àwọn ènìyàn nã sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀púpọ̀ lábẹ́ ìjọba rẹ̀, àti ní ti àwọn ilé, àti ni wúrà àti fàdákà, àti ní kíkó ọkà jọ, àti ní agbo ẹran, àti ọ̀wọ́ ẹran, àti nínú àwọn ohun tí a ti dá padà fún wọn. Moriántónì sì dàgbà púpọ̀, lẹ́hìnnã ní ó sì bí Kímù; Kímù sì jọba ní ìrọ́pò bàbá rẹ̀; ó sì jọba fún ọdún mẹ́jọ, bàbá rẹ̀ sì kú.O sì ṣe ti Kímù kò jọba nínú òdodo, nítorí eyi kò sì rí ojú rere Olúwa. Arákùnrin rẹ̀ sì dìde ọ̀tẹ̀ síi, nínú èyítí ó mũ ní ìgbèkùn; ó sì wà nínú igbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin nínú ìgbèkùn, àti nínú ọjọ́ ogbó rẹ̀ ní ó bí Léfì; ó sì kú. O sì ṣe tí Léfì sì sìn nínú ìgbèkùn lẹ́hìn ikú bàbá rẹ̀, fún ìwọ̀n ọdún méjìlélógójì. O sì gbé ogun tì ọba ilẹ̀ nã, nínú èyítí ó gbà ìjọba nã fún ìní ara rẹ̀. Àti lẹ́hìn tí ó ti gbà ìjọba nã fún ìní ara rẹ̀ ó ṣe èyítí ó tọ́ ní ojú Olúwa; àwọn ènìyàn nã sì ṣe rere ní ilẹ̀ nã; ó sì dàgbà púpọ̀, ó sì bí awọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin, ó sì bí Kórómù pẹ̀lú, ẹnití ó fí àmì òróró yàn lọ́ba ní ìrọ́pọ̀ ara rẹ̀. O sì ṣe tí Kórómù ṣe èyítí ó dara níwájú Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí ó pọ̀; àti lẹ́hìn tí ó ti rí ọjọ púpọ̀ ó sì kú, àní gẹ́gẹ́bí àwọn ara ayé; Kísì sí jọba ní ìrọ́pò rẹ̀. O sì ṣe tí Kíṣì kú pẹ̀lú, Líbù sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀. Ó sì ṣe tí Líbù pẹ̀lú ṣe ohun èyítí ó dára níwájú Olúwa. Àti ní ọjọ́ ayé Líbù wọ́n pa àwọn ejò olóró nã run. Nítorí eyi wọ́n lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù, látí lọ ṣe ọdẹ fun onjẹ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ nã, nítorítí àwọn ẹranko igbó bò ilẹ̀ nã. Líbù pẹ̀lú fúnrarẹ̀ sì di ọdẹ nla. Wọ́n sì kọ́ ìlú nlá kan sí ẹ̀bá ilẹ̀ tọ́ró tí ó wa ní ibití òkun tí pín ilẹ̀ nã yà. Wọ́n si pa ilẹ̀ tí ó wà ni apá gũsù aginjù mọ́ láti mã rí àwọn ẹran ọdẹ. Gbogbo orí ilẹ tí ó sì wà ní apá àríwá ni àwọn ènìyàn ngbé inú rẹ̀. Wọ́n s ì j ẹ́ ènìyàn t í ó tẹpámọ́ṣẹ́, wọ́n sì nṣe kárà-kátà wọn sì nṣòwò pẹ̀lú ara wọn, láti lè rí èrè. Wọ́n sì nlò onírúurú irin láti ṣiṣẹ́, wọn sì nyọ́ wúra, àti fàdákà, àti irin, àti idẹ, àti onírúuru àwọn irin; wọ́n sì nwà wọ́n jáde láti inú ilẹ̀; nítorí eyi wọ́n sì wà àwọn òkítì èrùpẹ̀ jáde láti ri àwọn irin àìpò tútù, ti wúrà, àti ti fàdákà, àti ti irin, àti ti bàbà. Wọ́n sì rọ àwọn onírúurú iṣẹ́ dáradára. Wọ́n sì ní àwọn aṣọ sẹ́dà, àti àwọn aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó jọjú; wọ́n sì nhun àwọn onírúurú aṣọ, kí wọn ó lè wọ asọ̀ láti fi bò ìhòhò wọn. Wọ́n sì rọ onírúuní àwọn ohun èlò láti roko, àti láti túlẹ̀ àti láti gbìn, láti kórè àti láti ro, àti láti pakà pẹ̀lú. Wọ́n sì rọ onírũru àwọn ohun èlò pẹ̀lú èyítí wọn mú àwọn ẹranko wọn ṣiṣẹ́. Wọ́n sì rọ onírúurú àwọn ohun ìjà ogun. Wọ́n sì nṣe onírúurú iṣẹ́ tí wọn ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára. Kò sì sí bí àwọn ènìyàn ti lè jẹ olùbùkún tó bí wọn ti jẹ́, àti kí ó mú wọn ṣe rere. Wọ́n sì wà nínú ilẹ̀ èyítí ó jẹ́ àṣàyàn jù gbogbo ilẹ̀ lọ, nítorítí Olúwa ni ó ti wí i. Ó sì ṣe tí Líbù gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ómọbìnrin; ó sì bí Héátómì pẹ̀lú. Ó sì ṣe tí Héátọ́mù jọba ní ìrọ́pò bàbá rẹ̀. Nígbàtí Héátómìsì ti jọba fún ọdún mẹ́rìnlélógún, ẹ kíyèsí i, wọ́n gbà ìjọba nã lọ́wọ́ rẹ̀. O sì lò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún nínú ìgbèkùn, bẹ̃ni, àní gbogbo èyítí ó kù nínú ọjọ́ ayé rẹ̀. O sì bí Hẹ́tì, Hẹ́tì sì gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Hẹ́tì sì bí Áárọ́nì, Áárọ́nì sì gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí Ámnígádà, Ámnígádà pẹ̀lú sì gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí Koríántúmù, Koríántúmù sì gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí Kọ́mù. Ó sì ṣe ti Kọ́mù fà ìdájì àwọn ènìyàn inú ìjọba nã lọ. Ó sì jọba lórí ìdaji ìjọba nã fún ọdún méjìlélógójì; ó sì lọ láti bá ọba Ámgídì jagun, wọ̀n sì jà fún ìwọ̀n ọdún tí ó pọ̀ nínú àkókò èyítí Kọ́mù gbà agbára lórí Ámgídì, ó sì gbà agbárá lórí èyítí ó kù nínú ìjọba nã. Ní ọjọ́ ayé Kọ́mù sì ni àwọn ọlọ́ṣà bẹ̀rẹ̀sí wà nínú ilẹ̀ nã; wọ́n sì mú àwọn ìlànà àtijọ́ lò, wọ́n sì ṣe àwọn ìbúra bí àwọn ará àtijọ́ ti nṣe, wọ́n sì wá ọ̀nà láti pa ìjọba nã run. Nísisìyí Kọ́mù sì bá wọn jà púpọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, kò borí wọn. 11 Àwọn ogun, iyapa, àtí ìwà búburú jọba láyé àwọn ara Járẹ́dì—Àwọn wòlĩ sọ àsọtẹ́lẹ̀ níti ìparun àwọn ará Járẹ́dì àfi bí wọ́n bá ronúpìwàdà—Àwọn ènìyàn nã kọ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ. Àwọn wòlĩ púpọ̀ sì wá pẹ̀lú ní ìgbà ayé Kọ́mù, wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ níti ìparun àwọn ènìyàn olókìkí nnì àfi bí wọ́n bá ronúpìwàdà, kí wọn ó sì yí sí ọ́dọ́ Olúwa, kí wọn sì kọ̀ ìpànìyàn àti ìwà búburú wọn sílẹ̀. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã ṣá àwọn wòlĩ nã tì, wọ́n sì sá lọ sí ọ̀dọ̀ Kọ́mù fún ãbò, nítorítí àwọn ènìyàn nã wá ọ̀nà láti pa wọ́n. Wọ́n sì sọ àsọtẹ́lé ohun púpọ̀ fún Kọ́mù; a sì bùkúnfún un ní ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀. Ó sì dàgbà púpọ̀, ó sì bí Ṣíblọ́mù; Ṣíblọ́mù sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀, Arákùnrin Ṣíblọ́mù sì ṣọ̀tẹ̀ sí i, ogun nla tí ó pọ̀ púpọ̀ sì bẹ́ sílẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ nã. O sì ṣe tí arákùnrin Ṣíblọ́mù mú kí wọn ó pa gbogbo àwọn wòlĩ tí ó nsọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ti ìparun àwọn ènìyàn nã; Ìyọnu nlá sì wà ní gbogbo ilẹ̀ nã, nítorítí wọ́n ti jẹ̃rí síi pé ègún nlá kan nbọ̀ lórí ilẹ̀ nã, àti lórí àwọn ènìyàn nã, àti pé ìparun nlá kan yíò wà ní ãrín wọn, irú èyítí kò sí rí lórí ilẹ̀ ayé, àwọn egungun wọn yíò sì di òkítì erùpẹ̀ lórí ilẹ̀ nã àfi bí wọ́n bá ronúpìwàdà kúrò nínú ìwà búburú wọn. Wọn kò sì gbọ́ ohùn Olúwa, nítorí àwọn ẹgbẹ́ buburu wọn; nítorí èyí, àwọn ogun àti ìgbóguntì bẹ́ sílẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ nã, àti pẹ̀lú àwọn ìyàn tí ó pọ̀ àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn, tóbẹ̃ ti ìparun nlá kan fi wà, irú èyítí ẹnikan kò mọ̀ rí lórí ilẹ̀ ayé; gbogbo èyí sì kọjá lọ ní ọjọ́ ayé Ṣíblọ́mù. Àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí ronúpìwàdà kúrò nínú àìṣedẽdé wọn; gẹ́gẹ́bí wọn sì ti ṣe èyí Olúwa sì ṣãnú fún wọn. O sì ṣe ti wọ́n pa Ṣíblọ́mù, wọ́n sì mú Sétì ní ìgbèkùn, ó sì gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. O sì ṣe tí Áháhì, ọmọ rẹ̀, sì gbà ijọba nã; ó sì jọba lórí àwọn ènìyàn nã ní gbogbo ayé rẹ̀. O sì ṣe onírúurú àìṣedẽdé ni ọjọ́ ayé rẹ̀, nípa èyítí ó mú kí wọn ó ta èjẹ̀ púpọ̀ sílẹ̀; ọjọ́ ayé rẹ̀ kò sì pọ̀. Àti Étémù, ẹnití í ṣe ìran Áháhì, sì gbà ìjọba nã; òun nã sì ṣe èyítí ó burú ní ojọ́ ayé rè. Ó sì ṣe ní ọjọ́ ayé Étémù tí àwọn wòlĩ púpọ̀ wá, wọ́n sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn nã; bẹ̃ni, wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ́ pé Olúwa yíò pa wọ́n run pátápátá kúrò lórí ilẹ̀ ayé àfi bí wọ́n bá ronúpìwàdà àwọn àìṣedẽdé wọn. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã sé ọkàn wọn le, tí wọn kò sì gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu; àwọn wòlĩ nã sì binújẹ́ wọ́n sì kúrò lãrín wọn. Ó sì ṣe tí Étémù sì ṣe ìdájọ́ nínú ìwà búburú ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí Mórọ̀n. Ó sì ṣe tí Mórọ̀n sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀; Mórọ̀n sì ṣe èyítí ó burú níwájú Olúwa. Ó sì ṣé tí ọ̀tẹ̀ sì dìde lãrín àwọn ènìyàn nã, nítorí ẹgbẹ́ òkùnkùn nnì èyítí wọn gbe dide láti ni agbara àti èrè; ènìyàn kan sì dìde lãrín wọn ẹnití ó lágbára nínú àìṣedẽdé, ó sì gbé ogun tì Mórọ̀n, nínú èyítí ó bì ìdajì ìjọba nã ṣubú; ó sì fi ọwọ́ mú ìdajì ìjọba nã fún ọpọ̀lọpọ̀ ọdún. Ó sì ṣe tí Mórọ̀n sì bì í ṣubú, ó sì gbà ìjọba nã padà. Ó sì ṣe tí ọkùnrin alágbára míràn dìde; ó sì jẹ́ ìran arákùnrin Járẹ́dì. Ó sì ṣe tí ó bì Mórọ̀n ṣubú ó sì gbà ìjọba nã; nítorí èyí Mórọ̀n gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí Koriántórì. Ó sì ṣe tí Koriántórì gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Àti ní ọjọ́ ayé Koriántórì àwọn wòlĩ púpọ̀ wá pẹ̀lú, wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípà àwọn ohun nlá èyítí ó yanilẹ́nu, wọ́n sì nkígbe ìrònúpìwàdà sí àwọn ènìyàn nã, àti pé àfi bí wọn bá ronúpìwàdà Olúwa Olọ́run yíò ṣe ìdájọ́ fún wọn sí ìparun wọn pátápátá; Àti pé Olúwa Olọ́run yíò rán tàbí mú àwọn ènìyàn míràn jáde láti ní ilẹ̀ nã ní ìní, nípa agbára rẹ̀, ní ọ̀na èyítí o gbà mú àwọn baba wọn jáde. Wọ́n sì kọ̀ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ nã, nítorí àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn àti àwọn ìwà ìkà ìríra wọn. O sì ṣe tí Koriántórì bí Étérì, ó sì kú, nígbàtí ó tí gbé nínú ìgbékùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 12 Wòlĩ Étérì gbà àwọn ènìyàn nã níyànjú láti gbà Ọlọ́run gbọ́—Mórónì ṣe àtúnsọ lórí àwọn ìyanu ati ohun ìyanu tí a ṣe nípa ìgbàgbọ́—Ìgbàgbọ́ ní ó jẹ́ kí arákùnrin Járẹ́dì ó rí Krístì—Olúwa a máa fún àwọn ènìyàn ní àìlera kí wọn ó lè rẹ̀ ara wọn sílẹ̀—Arákùnrin Járẹ́dì ṣí Okè-giga Sérínì nípa ìgbàgbọ́—Ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ jẹ àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì sí ìgbàlà—Mórónì rí Jésù lójúkojú. Ó sì ṣe tí ìgbà ayé Étérì jẹ́ ìgbà ayé Kóríántúmúrì; Kóríántúmúrì sì jẹ́ ọba lórí gbogbo ilẹ̀ nã. Étérì sì jẹ́ wòlĩ Olúwa; nítórí èyí Étérì jáde wá ní ìgbà ayéKóríántúmúrì, ó sì bẹ̀rẹ̀sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn nã, nítórítí wọn kò lè dá a lẹ́kun nítorí Ẹ̀mí Olúwa èyítí o wà nínú rẹ̀. Nítorítí ó kígbe láti òwúrọ̀, àní títí di àṣalẹ́, tí ó ngbà àwọn ènìyàn nã níyànjú láti gbàgbọ́ nínú Olọ́run sí tí ìrònúpìwàdà kí wọn ó má bã parun, ó sì nwí fún wọn pé nípa ìgbàgbọ́ ohun gbogbo a má a di mímúṣẹ— Nítorí èyí, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run lè ní ìrètí dájúdájú fún ayé tí ó dára jù èyí, bẹ̃ni, àní àyè ní apá ọ̀tún Ọlọ́run, ìrètí èyítí nwá nípa ìgbàgbọ́, tí ó sì rọ̀ mọ́ ọkàn ènìyàn, típẹ́típẹ́, èyítí yíò mú wọn dúró gbọningbọnin àti ní ìdúróṣínṣin, tí wọn sì kún fún iṣẹ́ rere ní gbogbo ìgbà, tí a sì darí wọn láti yìn Ọlọ́run lógo. Ó sì ṣe tí Étérì sì nsọ àsọtélẹ̀ níti àwọn ohun nlá èyítí ó yanilẹ́nu sí àwọn ènìyàn nã, èyítí wọn kò gbàgbọ́, nítorípé wọn kò rí wọn. Àti nísisìyí, èmi Mórónì, yíò sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn ohun wọ̀nyí; èmi yíò fihàn sí aráyé pé ìgbàgbọ́ jẹ́ àwọn ohun tí a ní írètí fún tí a kò fi ojú rí; nítorí eyi, ẹ máṣe jiyàn nítorípé ẹ̀yin kò ríi, nítorítí ẹ̀yin kì yíò rí ẹ̀rí gbà títi di lẹ̀hìn tí a bá dán ìgbàgbọ́ yín wò. Nitori nípa ìgbàgbọ́ ni Krístì fi ara rẹ hàn sí àwọn baba wa, lẹ́hìn tí ó ti jínde kúrò nínú òkú; kò sì fi ara rẹ̀ hàn sí wọn títí dí ní ẹ̀hìn ìgbà tí wọn ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀; nítorí èyí, ó dì dandan pé kí àwọn kan ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, nítorítí kò fi ara rẹ̀ hàn sí aráyé. Ṣùgbọ́n nítorí ìgbàgbọ́ ènìyàn ó ti fi ara rẹ̀ hàn sí aráyé, ó sì ṣe orúkọ Bàbá lógo, ó sì pèsè ọ̀nà kan sílẹ̀ nípasẹ̀ èyítí àwọn míràn yíò jẹ́ alábãpín nínú ẹ̀bùn ọ̀run nã, nípasẹ̀ èyítí wọn yíò ní ìrètí lórí àwọn ohun nã tí wọ́n kò tĩ rí. Nítorí èyí, ẹ̀yin lè ní ìrètí pẹ̀lú, kí ẹ sì jẹ́ alábãpín nínú ẹ̀bùn nã, bí ẹ̀yin ó bá ní ìgbàgbọ́. Ẹ kíyèsĩ nípa ìgbàgbọ́ ni a fi pè àwọn ará ìgbà àtijọ́ nípa ti àṣẹ mímọ́ ti Ọlọrun. Nítorí èyí, nípa ìgbàgbọ́ ni a fi òfin Mósè fún ni. Sùgbọ́n nínú ẹ̀bùn tí í ṣe Ọ́mọ rẹ̀ ni Olọ́run pèsè ọ̀nà èyítí ó dára jù; àti nípa ìgbàgbọ́ ní a sì ti múu ṣẹ. Nítorí bí kò básí ìgbàgbọ́ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn Ọlọ́run kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu lãrín wọn; nítorínã, òun kò fi ara rẹ̀ hàn àfi ní ẹ́hìn ìgbàgbọ́ wọn. Ẹ kíyèsĩ, ìgbàgbọ́ Álmà àti Ámúlẹ́kì ní ó mú kí tũbú wo lulẹ̀. Ẹ kíyèsĩ, ìgbàgbọ́ Nífáì àti Léhì ní ó mú kí ìyípadà ó bá àwọn ara Lámánì, tí a fi ṣe ìrìbọmi wọn pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ kíyèsĩ, ìgbàgbọ́ Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó mú kí a ṣe iṣẹ́ ìyanu nla lãrín àwọn ará Lámánì. Bẹ̃ni, àní àti gbogbo àwọn tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ ìyanu ṣe wọ́n nípa ìgbàgbọ́, àní àwọn tí wọ́n wà ṣãju Krístì àti àwọn tí o wà lẹ́hìn rẹ̀. Nípa ìgbàgbọ́ sì ní àwọn ọmọ ẹ̀hìn mẹta nã gbà ìlérí pé wọn kò ní tọ́ ikú wò; wọ́n kò sì gbá ìlérí nã àfi ní ẹ́hìn ìgbàgbọ́ wọn. Kò sì sí ìgbà kan tí ẹnikẹ́ni ṣe iṣẹ́ ìyanu àfi ní ẹ́hìn ìgbàgbọ́wọn; nítorí èyí wọ́n kọ́kọ́ gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run. Àwọn púpọ̀ ní ó sì wà tí ìgbàgbọ́ wọn lágbára púpọ̀, àní kí Krístì ó tó dé, àwọn tí a kò lè dènà mọ́ ní ibi ìkèlé, sùgbọ́n tí wọn rí i pẹ̀lú ojú ara wọn àwọn ohun tí wọn ti fi ojú ìgbàgbọ́ wò, tí inú wọn sì dùn. Ẹ sì kíyèsĩ, àwa ti ríi nínú àkọsílẹ̀ yĩ pé ọ̀kan nínú wọn ní àrákurin Járẹ́dì; nítorítí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run tóbi tóbẹ̃ tí Olọ́run kò lé fi ìka rẹ̀ pamọ́ kúrò lójú arákùnrin Járẹ́dì nígbàtí Ọlọ́run nà ìka rẹ̀ jáde, nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ti sọ fún un, ọ̀rọ̀ èyítí ó tí rí gbà nípa ìgbàgbọ́. Àtí lẹ́hìn tí arákùnrin Járẹ́dì ti ri ìka Olúwa, nítorí ìlérí tí arákùnrin Járẹ́dì ti rí gbà nípa ìgbàgbọ́, Olúwa kò lè dáwọ́ ohunkóhun dúró fún un láti rí; nítorí èyí ó fi ohun gbogbo hàn sí nítorítí a kò lè fí í sílẹ̀ ní àìsí ìkèlé. Àti nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn baba mi ti rí ìlérí nã gbà pé àwọn ohun wọ̀nyí yíò tọ̀ àwọn arákùnrin wọn wá nípasẹ̀ àwọn Kèfèrí; nítorí èyí Olúwa ti pàṣẹ fún mi, bẹ̃ni, àní Jésù Krístì. Èmi sì wí fún un pé: Olúwa, àwọn Kèfèrí yíò fí àwọn ohun wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́yà, nítorí àìpé wa nínú ohun kíkọ; nítorítí Olúwa ìwọ ní ó mú kí àwa ó tobi nínú ọ̀rọ̀ sísọ nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò mú kí àwa ó tóbi níti ohun kíkọ; nítorítí ìwọ ni ó mú kí gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí ó lè sọ̀rọ̀ púpọ̀ nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ èyítí ìwọ tí fi fún wọn; Ìwọ sì ti mú kí àwa ó lè kọ ṣùgbọ́n díẹ̀, nítorí ìnira ọwọ́ wa. Kíyèsĩ, ìwọ kò mú wa tóbi nínú ohun kíkọ bí ti arákùnrin Járẹ́dì, nítorítí ìwọ mú kí àwọn ohun tí ó kọ ó tóbi àní gẹ́gẹ́bí ìwọ ti rí, sí fífi ipá mú ènìyàn láti kà wọ́n. Ìwọ sì ti mú kí àwọn ọ̀rọ̀ wa ó ní ágbára àti kí wọn ó tóbi, àní tó èyíti a kò lè kọ wọ́n; nítorí èyí, nígbàtí àwa nkọ àwa rí àìpé wa, àwa sì nṣe àṣìṣé níti bí a ṣe nkọ àwọn ọ̀rọ̀ wa; èmi sì bẹ̀rù kí àwọn Kèfèrí ó má fi àwọn ọ̀rọ̀ wa ṣe ẹlẹ́yà. Nígbàtí èmí si ti sọ eleyĩ, Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ wípé: Àwọn aṣiwèrè ènìyan a mã ṣe ẹlẹ́yà, ṣùgbọ́n wọn yíò ṣọ̀fọ̀; ọ́re-ọ̀fẹ́ mí sì tó fún oniwàtútù ènìyàn, kí wọn ó má lè rí ọ mú nítí àìpé rẹ; Bí àwọn ènìyàn bà sì tọ̀ mi wá emí yíò fi àìpé wọn hàn sí wọn. Mo fún àwọn ènìyàn ní àìpé kí wọn ó lè rẹ̀ ara wọn sílẹ̀; ọ́re-ọ̀fẹ́ mi sì tó fún gbogbo ẹ̀nìti ó bá rẹ̀ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi; nítorí tí wọ́n bá rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ níwájú mi, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi nígbànã ni èmi yio mú àwọn ohun aláìlágbára dì èyíti ó lágbára fún wọn. Ẹ kíyèsĩ, èmi yíò fi àìlera àwọn Kèfèrí hàn sí wọn, èmi yíò sì fi hàn sí wọn pé ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ a mã mú wá sí ọ́dọ̀ mi—orísun gbogbo òdodo. Àti èmi Mórónì, lẹ́hìn tí mo ti gbọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ní ìtùnú, mo sì wípé: A! Olúwa, àwa yíò ṣe òdodo rẹ, nítorítí mo mọ̀ pé ìwọ nṣe fún àwọn ọmọ ènìyàn gẹgẹbí ìgbàgbọ́ wọn; Nítorítí arákùnrin Járẹ́dì wí fún òkè gíga Sérínì pé, Ṣí ní ìdí—a sì ṣí i ní ìdí. Bí kò bá sìní ìgbàgbọ́ kì bá tí ṣí ní ìdì; nítorí èyí ìwọ a máa ṣe fun àwọn ènìyàn lẹ́hìn tí wọn bá ní ìgbàgbọ́. Nítorí báyĩ ní ìwọ fí ara rẹ hàn sí àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ; lẹ́hìn tí wọn ní ìgbàgbọ́, tí wọn sì sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ, ìwọ sì fi ara rẹ hàn sí wọn ninu agbára nlá. Èmi sì rántí pẹ̀lú pé ìwọ ti wípé ìwọ ti pèsè ilé fún ènìyàn, bẹ̃ni, àní lãrín àwọn ibùgbé Baba rẹ, nínú èyítí èníyàn lè ni ìrètí tí ó dara púpọ̀; nítorí èyí ènìyàn gbọ́dọ̀ ní ìrètí, bí kò rí bẹ̃ kò lè rí ibi ìjogún nínú ibi èyíti ìwọ ti pèsè sílẹ̀. Àti pẹ̀lú, mo rántí pé ìwọ ti wípé ìwọ ti ní ìfẹ́ sí ayé, àní sí fífi ẹ̀mí ara rẹ lélẹ̀ fún ayé, kí ìwọ ó tún padà mú u láti pèsè àyè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn. Àti nísisìyí èmi mọ̀ pé ìfẹ́ yì èyítí ìwọ ti ní fún àwọn ọmọ ènìyàn jẹ́ ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́; nítorí èyí, àfi bí àwọn ènìyàn bá ni ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ wọn kò lè jogún ibi èyítí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ nínú àwọn íbùgbé Bàbá rẹ. Nítorí èyí, èmi mọ̀ nípa ohun yĩ tí ìwọ ti wí, pé bí àwọn Kèfèrí kò bà ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, nitori àìpé wa, pé ìwọ yíò dán wọn wò ìwọ ó sì gbà tálẹ́ntì nã lọ́wọ́ wọn, bẹ̃ni, eyi nnì ti wọ́n ti rí gbà, kí ó sì fifún àwọn ti yíò ní lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó sì ṣe tí mo gbàdúrà sí Olúwa kí ó lè fún àwọn Kèfèrí ní ọ́re-òfẹ́, kí wọn ó lè ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́. Ó sì ṣe tí Olúwa wí fún mi pe: Bí wọn kò bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ kò já mọ́ nkan fún ọ, ìwọ ti jẹ olótĩtọ́; nítorí èyí, á ó mú ẹ̀wu rẹ mọ́. Àti nítorípé ìwọ ti ri àìlera ara rẹ a ó mú kí ó ní ágbára, àní sí jíjókọ́ ní ãyè nã èyítí èmi ti pèsè sílẹ̀ nínú àwọn ibùgbé Bàbá mi. Àti nísisìyí èmi, Mórónì, kí àwọn Kèfèrí pé o digbóṣe, bẹ̃ni, àti pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi ti èmi ní ìfẹ́ sí, títí a ó fi pàdé níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì, níbití gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ pé ẹ̀jẹ̀ yín kò fi àbàwọ́n sí ẹ̀wù mi. Nígbànã ni ẹ̀yin yíò mọ̀ pé emí ti ri Jésù, àti pé ó ti bá mi sọ̀rọ̀ lójúkojú, àti pé ó wí fún mi nínú ìwà-ìrẹ̀lẹ̀ tí ó hàn kedere, àní bí ẹnìkan ti í ba ekeji sọ̀rọ̀ ní èdè mi, nípa àwọn ohun wọ̀nyí; Díẹ̀ nínú àwọn ohun wọ̀nyí ni èmi sì kọ, nítorí àìpé mí nínú ohun kíkọ. Áti nísisìyí, èmi yíò gbà yín níyànjú láti wá Jésù yĩ kiri nípa ẹniti àwọn wòlĩ àti àwọn àpóstélì ti kọ, pé kí ọ́re ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Baba, àti pẹ̀lú Jésù Krístì Olúwa, àti Ẹ̀mí Mímọ́, ẹniti ó njẹ́rĩ sí wọn, ó wà, kí ó sì máa gbé nínú yín títí láé. Amín. 13 Étérì sọ̀rọ̀ nípa Jerúsálẹ́mù Titun kan èyítí irú ọmọ Jósẹ́fù yíò kọ́ sí Amẹ́ríkà—O sọ àsọtẹ́lẹ̀, wọn lé e jáde, o kọ ìtàn àwọn ara Járẹ́dì, ó sì sọ àsọtélẹ̀ níti iparun àwọn ara Járẹ́dì—Ogun jà lórí gbogbo ilẹ̀ nã. Àti nísisìyí èmi, Mórónì, tẹ̀síwájú láti pari àkọsílẹ̀ èyítí èmi nkọ nípa ìparun àwọn ènìyàn nã tí mo ti nkọ nípa wọn. Nítorí ẹ kíyèsĩ, wọ́n ṣá gbogbo ọ̀rọ̀ Étérì tì; nítorítí ó sọ fúnwọn nítọ́tọ́ nípa ohun gbogbo, láti ìbẹ̀rẹ̀ ènìyàn; àti pé lẹ́hìn tí àwọn omi ti fà sẹ́hìn kúrò lórí ilẹ̀ yĩ ó di ilẹ̀ tí ó dárajù gbogbo ilẹ̀ míràn lọ, ilẹ̀ tí Olúwa yàn; nítorí èyí Olúwa nfẹ́ kí gbogbo ènìyàn tí ngbé orí ilẹ̀ nã ó sìn òun; Àti pé ó jẹ́ ibití Jerúsálẹ́mù Titun nã yíò wà, èyítí yíò sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀run, àti pé yíò jẹ́ ibi mímọ́ Olúwa. Sì kíyèsĩ, Étérì rí àwọn ọjọ́ Krístì, ó sì sọ̀rọ̀ nípa Jerúsálẹ́mù Titun kan lórí ilẹ̀ yĩ. Ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú nípa ìdílé Ísráélì, àti Jerúsálẹ́mù nnì nínú èyítí Léhì yíò jáde wá—lẹ́hìn tí a bá sì ti pa á run a ó tún padà tún un kọ́, ìlú mímọ́ sí Olúwa; nítorí èyí, kò lè jẹ́ Jerúsálẹ́mù àkọ̀tun nítorítí ó ti wà tẹ́lẹ̀rí ní ìgbà àtijọ́; sùgbọ́n a ó tún padà tún un kọ́, yíò sì di ìlú mímọ́ tí í ṣe ti Olúwa; a ó sì kọ́ ọ fún ìdílé Isráẹ́lì— Àti pé a ó kọ́ Jerúsálẹ́mù Titun kán sí órí ilẹ̀ yĩ, sí ìyókù irú-ọmọ Jósẹ́fù, àwọn ohun ti irú rẹ̀ ti wà rí. Nítorí gẹ́gẹ́bí Jósẹ́fù ti mú bàbá rẹ̀ jáde wá sínú ilẹ̀ Égíptì, àní tí ó kú sí ibẹ̀; nítorí èyí, Olúwa mú ìyókù irú-ọmọ Jósẹ́fù jáde kúrò nínú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, kí ó lè fi ãnú hàn sí irú-ọmọ Jósẹ́fù kí wọn ó má bã ṣègbé, gẹ́gẹ́bí ó ti fí ãnú hàn sí bàbá Jósẹ́fù kí ó ma bã ṣègbé. Nítorí èyí, ìyókù ìdílé Jósẹ́fù ni a ó kọ́ lórí ilẹ̀ yĩ, yíò sì jẹ́ ilẹ̀ ìní wọn; wọn yíò sì kọ ìlú mímọ́ kan sí Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Jerúsálẹ́mù ti ìgbà àtijọ́; a kì yíò sì fọ́n wọn ká mọ, títí òpin yíò dé nígbàtí ayé yíò kọjá lọ. Ọ̀run titún kan yíò sì wà àti ayé titun; wọn yíò sì rí bí ti ìgbà àtijọ́, àfi pé àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ, ohun gbogbo sì ti di titun. Nígbànã ni Jerúsálẹ́mù Titun yíò dé; alábùkún-fún sì ni àwọn tí ngbé inú rẹ̀, nítorípé àwọn ni ẹnití aṣọ wọn di funfun nípa ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn; àwọn sì ní àwọn tí a ó kà mọ́ àwọn ìyókù irú-ọmọ Jósẹ́fù, tí wọn jẹ́ ara ìdílé Ísráẹ́lì. Nígbànã pẹ̀lú ní Jerúsálẹ́mù ìgbà àtijọ́ yíò dé; ti àwọn tí ngbé inú rẹ̀, yíò jẹ́ alábùkún-fún, nítorítí a ti wẹ̀ wọ́n nínú èjẹ́ Ọ̀dọ́-àgùtàn; àwọn sì ni ẹnití Olúwa fọnká tí ó sì kójọ papọ̀ láti igun mẹ́rẹ̀rin ayé, àti láti àwọn orilè-èdè apá àríwá, tí wọ́n sì jẹ́ alábãpín nítí ìmúṣẹ májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú bàbá wọn, Ábráhámù. Àti nígbàtí àwọn ohun wọ̀nyí bá dé, ìwé-mímọ́ yíò sì di mímúṣẹ èyítí ó wípé àwọn kan wà tí ó jẹ ẹni-àkọ́kọ́, tí yíò si di ẹni-ikẹhìn; àwọn kan sì wà tí ó jẹ́ ẹni ìkẹhìn, tí yíò sì jẹ́ ẹni-àkọ́kọ́. Èmi sì múra láti kọ síi, ṣùgbọ́n a dá mi lẹ́kun; sùgbọ́n títóbi àti ìyanu ni àwọn ìsọtẹ́lẹ́ Étérì jẹ́; ṣùgbọ́n wọn kã sí ẹniasán, wọ́n sì lée jáde; ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́ nínú ihò inú àpáta kan ní ọ̀sán, àti ní àṣálẹ́ ó jáde sí ìta ó sì nwò àwọn ohun tí yíò débá àwọn èníyàn nã. Bí ó sì ti ngbé inú ihò inu àpáta nã ó kọ ìyókù àwọn àkọsílẹ̀ yĩ, tí ó sì nwò àwọn ìparun tí ó débá àwọn ènìyàn nã, ní àsálẹ́. Ó sì ṣe nínú ọdún kannã nínú èyítí a lée jáde kúrò lãrín àwọn ènìyàn nã, ogun nlá kan bẹ́ sílẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn nã, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ó jáde wá, tí wọn jẹ alágbára ènìyàn, tí wọ́n sì nlepa láti pa Kóríántúmúrì run nípa àwọn ète òkùnkùn ìwà búburú wọn, nípa èyítí a ti sọ. Àti nísisìyí Kóríántúmúrì, nítorítí òun tìkárarẹ̀ kọ́ nípa gbogbo àwọn ìmọ̀ nípa ogun jíjà àti gbogbo ọgbọ́n àrekérekè ayé, nítori èyí ó gbé ogun tì àwọn tí wọn lépa láti pã run. Ṣùgbọ́n kò sì ronúpìwàdà, bẹ̃ nã ni àwọn arẹwà ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀; tàbí àwọn arẹwà ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Kóhọ̀; tàbí àwọn arẹwà ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Kóríhọ̀; àti ní kúkúrú, kò sí èyíkéyí nínú àwọn arẹwà ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin lórí ilẹ̀ ayé gbogbo tí ó ronúpìwàdà nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí èyí, ó sì ṣe nínú ọdún kíni tí Étérì gbé inú ihò àpáta, àwọn ènìyàn púpọ̀ sì ni àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn fi idà pa, tí wọ́n nbá Kóríántúmúrì jà láti lè gba ìjọba nã. Ó s ì ṣ e àwọn ọmọ Kóríántúmúrì ja púpọ̀ wọn sì fi ẹ̀jẹ̀ ṣòfò púpọ̀. Àti nínú ọdun kejì ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ Étérì wá, pé kí ó lọ kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Kóríántúmúrì pe, bí ó bá ronúpìwàdà, àti gbogbo ilé rẹ̀, Olúwa yíò fi gbogbo ìjọba rẹ̀ fún un yíò sì dá àwọn ènìyàn rẹ̀ sí— Bíkòjẹ́bẹ̃ a ó pa wọ́n run, àti gbogbo ilé rẹ̀ àfi òun nìkan. Àti pé òun yíò wà lãyè kí ó lè rí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nã èyítí a ti sọ nípa rẹ̀ níti àwọn ènìyàn míràn tí yíò gbà ilẹ̀ nã ní ìní; àti pé àwọn ni yíò sin òkú Kóríantúmúrì; àti pé gbogbo ẹ̀mí ni a ó parun àfi Kóríántúmúrì. Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì kò ronúpìwàdà, bẹ̃ nã ni ìdílé rẹ̀, tàbí àwọn ènìyàn nã; àwọn ogun kò sì dá dúró; wọn sì nwa ọ̀na láti pa Étérì, ṣùgbọ́n ó sá kúrò níwájú wọn ó sì tún sápamọ́ sínú ihò àpáta. Ó si ṣe tí Ṣárẹ́dì dìde, òun pẹ̀lú sì gbógun tì Kóríántúmúrì; ó sì nã, tóbẹ̃ tí ó sì múu sínú ìgbèkùn ní ọdún kẹta. Àwọn ọmọ Kóríántúmùrì, nínú ọdún kẹrin, sì nà Ṣárẹ́dì, wọ́n sì gbà ìjọba nã padà fún bàbá wọn. Nísisìyí ogun bẹ̀rẹ̀sí wà lórí ilẹ̀ nã gbogbo, olukúlùkù pẹ̀lú ẹgbẹ́ rẹ̀ sì njà fún èyítí ó wù ú. Àwọn ọlọ́sà sì wà, àti ní kúkúrú, onírúurú ìwà búburú wà lórí ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì bínú sí Ṣárẹ́dì gidigidi, ó sì jáde lọ kọlũ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ̀; wọ́n sì bá ara wọn pàdé nínú ìbínú nlá, wọ́n sì pàdé nínú àfonífojì Gílgálì; ogun nã sì gbóná gidigidi. O sì ṣe tí Ṣárẹ́dì bá a jà fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta. O sì ṣe tí Kóríántúmúrì nã, ó sì lée títí ó fi wọ̀ àwọn ilẹ̀ títẹ́jú ti Hẹ́ṣlọ́nì. O sì ṣe tí Ṣárẹ́dì tún jagun pẹ̀lú rẹ̀ lórí àwọn ilẹ̀ tí ó tẹ́jú nã; ẹ sì kíyèsĩ, ó sì nà Kóríántúmúrì, ó sì tún lée padà sínú àfonífojì Gílgálì. Kóríántúmúrì sì tún bá Ṣárẹ́dì jagun nínú àfonífojìGílgálì, nínú èyítí ó nà Ṣárẹ́dì tí ó sì pã. Ṣárẹ́dì sì ṣa Kóríántúmúrì lọ́gbẹ́ ní itan rẹ̀, tí o jẹ wípé kò jáde lọ jagun mọ́ fún ìwọ̀n ọdún méjì, nínú àkókò tí gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ nã nta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ti kò sì sí ẹnití yíò dá wọn lẹ́kun. 14 Àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã, mú ègún wá sí órí ilẹ̀ nã—Kóríántúmúrì wọnú ogun lọ pẹ̀lú Gíléádì, lẹ́hìnnã Líbù, àti lẹ́hìnnã Ṣísì—Ẹjẹ̀ àti ìpakúpa ènìyàn bò ilẹ̀ nã. Àti nísisìyí ègun nlá kan bẹ̀rẹ̀sí wà lórí ilẹ̀ nã nítorí àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã, nínú èyítí bí ẹnikẹ́ni bá fi ohun èlò rẹ̀ tàbí idà rẹ̀ sílẹ̀ lórí pẹpẹ rẹ̀, tàbí lórí ibití óun nfií pamọ́ sí, ẹ kíyèsĩ, ní ọjọ́ kejì, kò ní ríi mọ́, bẹ̃ ni ègún tí ó wà lórí ilẹ̀ nã pọ̀ tó. Nítorí èyí olukúlùkù dì èyítí í ṣe tirẹ̀ mú, mọ́ ọwọ ara rẹ̀, tí kò sì tọrọ lọ́wọ́ ènìyàn bẹ̃ni kò yá ènìyàn ní ohunkan; olukúlùkù sì mú èkù idà rẹ̀ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọwọ òtún rẹ̀, ní ìdábòbò ohun ìní rẹ̀ àtí ẹ̀mí ara rẹ̀ àti ti àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀. Àti nísisìyí, lẹ́hìn ìwọ̀n ọdún méjì, àti lẹ́hìn ikú Ṣárẹ́dì, ẹ kíyèsĩ, arákùnrin Ṣárẹ́dì dìde ó sì gbé ogun tì Kóríántúmúrì, nínú èyítí Kóríántúmúrì nàa tí ó sì lée lọ sínú aginjù Ákíṣì. Ó sì ṣe tí arákùnrin Ṣárẹ́dì sì gbe ogun tì í nínú aginjù Ákíṣì; ogun nã sì gbóná gidigidi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ní wọ́n sì fi idà pa. Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì sì ká a mọ́ inú aginjù, arákùnrin Ṣárẹ́dì sì kọjá lọ jáde kúrò nínú aginjù ní òru, ó sì pa nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì, nítorípé wọ́n tí mutí yó. Ó si wá sínú ilẹ̀ Mórọ̀n, ó sì fi ara rẹ̀ sí órí ìtẹ́ Kóríántúmúrì. Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì ngbé pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ nínú aginjù fún ìwọ̀n ọdún méjì, nínú èyítí ó rí àwọn ọmọ ogun púpọ̀ síi. Nísisìyí arákùnrin Ṣárẹ́dì, ẹnití orúkọ rẹ̀ í ṣe Gíléádì, pẹ̀lú rí àwọn ọmọ ogun púpọ̀ síi, nítorí àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn. Ó si ṣe tí olórí àlùfã rẹ̀ pã bí ó ti jóko lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì ṣe tí ọ̀kan nínú àwọn egbẹ́ òkùnkùn nã pa lójú ọ̀nà kọ̀rọ̀ kan, ó sì gbà ijọba nã tìkárarẹ̀; orúkọ rẹ̀ sì ni Líbù; Líbù sì jẹ ènìyan tí ó ga púpọ̀, jù ẹnikẹ́ni lọ lãrín gbogbo àwọn ènìyàn nã. Ó sì ṣe nínú ọdún èkíní ìjọba Líbù, Kóríántúmúrì gòkè wá sínú ilẹ̀ Mórọ̀n, ó sì gbé ogun tì Líbù. Ó sì ṣe tí ó bá Líbù jà, nínú èyítí Líbù ṣáa ní apá rẹ̀ tí ó sì gbọgbẹ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì tẹ̀lé Líbù, tí ó sì sálọ sí ibi agbègbè etí-ìlu ní etí òkun. Ó sì ṣe ti Kóríántúmúrì sá tẹ̀lée; Líbù sì gbé ogun tĩ ní etí òkun. Ó sì ṣe tí Líbù sì lù ẹgbẹ ọmọ ogun Kóríántúmúrì, tí wọ́n sì tún sá sínú aginjù Ákíṣì. Ó sì ṣe tí Líbù sì sá tèlée títí ó fi dé ibi àwọn ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ti Ágọ́ṣì. Kóríántúmúrì sì ti kógbogbo àwọn ènìyàn nã pẹ̀lú rẹ̀ bí ó ti salọ níwájú Líbù ní agbègbè ilẹ̀ tí ó sálọ sí. Nígbàtí ó sì dé ibi àwọn ilẹ tí ó tẹ́jú ti Ágọ́ṣì, ó gbé ogun tì Líbù, ó sì fí idà sáa títí ó fi kú; bíótilẹ̀ríbẹ̃, arákùnrin Líbù sì dojúkọ Kóríántúmúrì dípò rẹ̀, ogun nã sì dì èyítí ó gbóná gidigidi, nínú èyítí Kóríántúmúrì tún sa kúrò níwájú ọmọ ogun arákùnrin Líbù. Nísisìyí orúkọ arákùnrin Líbù ni Ṣísì. Ó sì ṣe tí Ṣísì sá tẹ̀lé Kóríántúmúrì, ó sì ṣẹ́gun ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá, ó sì pa àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, ó sì sun àwọn ìlú-nlá nã níná. Ìbẹ̀rù fún Ṣísì sì lọ jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, igbe kan tàn jákè-jádò ilẹ̀ nã pe—Tani ó lè dúró níwájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ṣísì? Ẹ́ kíyèsĩ, ó gbá ilẹ̀ ayé níwájú rẹ̀! Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí wọ́ pọ̀ nínú agbo, jákèjádò gbogbo orí ilẹ̀ nã. Wọ́n sì pínyà; apá kan nínú wọn sì sá sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ṣísì, apá kan sì sá sínú egbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì. Ogun nã sì pọ̀ ọjọ́ rẹ̀ sì pẹ́, ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìpànìyàn nípakúpa nã sì wà fún ọjọ́ pípẹ́, ti ara àwọn òkú ènìyàn bò gbogbo orí ilẹ̀ nã. Ogun nã sì ṣe kánkán tí kò sí ẹnikẹ́ni tí ó kù láti sin àwọn òkú, sùgbón wọ́n ntẹ̀síwájú láti ìtàjẹ̀sílẹ̀ dé ìtàjẹ̀sílẹ̀, tí wọ́n sì nfi àwọn ara àti ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé sílẹ̀ ní fífọ́nká lórí ilẹ̀ nã, láti di onjẹ fún àwọn ìdin tí íjẹ ẹran ara. Òórùn rẹ̀ sì tàn ká orí ilẹ̀ nã, àní ká orí gbogbo ilẹ̀ nã; nítorí èyí àwọn ènìyàn nã ní ìpọ́njú ní ọ̀san àti ní òru, nítorí ọ́rùn rẹ̀. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Ṣísì kò dẹ́kun láti lé Kóríántúmúrì; nítorítí ó tí búra láti gbèsan lára Kóríántúmúrì níti ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ̀, ẹnití ó ti pa, àti ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ̀ Étérì wá pé a kò ní fi idà pa Kóríántúmúrì. Àti báyĩ àwa ríi pé Olúwa bẹ̀ wọ́n wò ní ẹ̀kún ìbínú rẹ̀, àwọn ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra wọn ní ó ti pèsè ọ̀nà sílẹ̀ fún ìparun wọn títi ayé. O si ṣe tí Ṣísì sì lé Kóríántúmúrì lọ sí apá ìlà-oòrùn, àní dé ibi etí-ìlú tí ó wà ní etí-òkun, níbẹ̀ ní ó sì gbé ogun tì Ṣísì fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta. Ìparun tí ó wà lãrín àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ṣísì sì burú tóbẹ̃ tí àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀rù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sálọ níwájú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì; wọ́n sì sálọ sínú ilẹ̀ Kóríhọ̀, wọ́n sì gbá gbogbo àwọn tí ngbé inú rẹ̀ níwájú wọn, gbogbo àwọn tí kò darapọ̀ mọ́ wọn. Wọ́n sì pàgọ́ wọn sínu àfonífojì Kóríhọ̀; Kóríántúmúrì sì pàgọ́ rẹ̀ sínú àfonífoji Ṣũrì. Nísisìyí àfonífojì Ṣũrì súnmọ́ òkè Kómnórì, nítorí èyí, Kóríántúmúri sì ko àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun jọ lórí òkè Kómnórì, ó sì fọn fèrè sí àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun Ṣísì láti pè wọ́n sí ìjà. Ó sì ṣe ti wọ́n jáde wá, ṣùgbọ́n wọ́n tún lé wọn padà; wọ́n sì wá ní ìgbà kejì, wọ́n sì tún lé wọn padà ní ìgbà keji. Ó sì ṣe ti wọn tún wá ní ìgbà kẹta, ogun nã sì gbóná gidigidi. O si ṣe tí Ṣísì fi idà ṣá Kóríántúmúrì tí ó sì ṣá a lọ́gbẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀; Kóríántúmúrì nítorípé ó pàdánù ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, o sì dákú, wọ́nsì gbé e lọ bí ẹnití ó kú. Nísisìyí àdánù lórí àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ní apá méjẽjì pọ̀ púpọ̀ tí Ṣísì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé kí wọn ó má sátẹ̀lé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì mọ́, nítorí èyí, wọ́n padà sí ibùdó wọn. 15 Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àwọn ara Jarẹ́dì ni wọ́n pa nínú ogun—Ṣísì àti Kóríántúmúrì kó gbógbo àwọn ènìyàn nã jọ sí ìjà àjàkú—Ẹ̀mí Olúwa dẹ́kun láti mã bá wọn jà—Ọrilẹ̀ èdè àwọn ará Járẹ́dì ni a parun pátápátá—Kóríántúmúrì nìkan ní ó kù lẹ́hìn. Ó sì ṣe nígbàtí Kóríántúmúrì ti bọ̀sípò ní ti àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀sí rántí àwọn ọrọ̀ tí Étérì ti sọ fún un. Ó rí í pé wọ́n ti fi idà pa àwọn tí ó fẹ́rẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún méjì nínú àwọn ènìyàn rẹ̀, ó si bẹ̀rẹ̀sí ní irora ọkàn nínú ọkàn rẹ̀; bẹ̃ni, wọ́n ti pa ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún méjì àwọn ọkùnrin alágbára, àti pẹlú àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn. O sì bẹ̀rẹ̀sí ronúpìwàdà kúrò nínú ohun búburú tí ó ti ṣe; ó bẹ̀rẹ̀sí rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ fún un láti ẹnu gbogbo àwọn wòlĩ, ó sì rí i pé, wọ́n ti dì mímúṣẹ títí di àkókò yĩ, títí dé èyítí ó kéré jùlọ; ọkàn rẹ̀ sì sọ̀fọ̀ ó sì kọ̀ láti gbà itùnú. Ó sì ṣe tí ó kọ èpístélì kan sí Ṣísì, pé òun fẹ́ kí ó dá àwọn ènìyàn nã sí, àti pe òun yíò gbé ìjọba nã lélẹ̀ nítorí ẹ̀mi àwọn ènìyàn nã. O sì ṣe nígbàtí Ṣísì tí rí èpístélì rẹ̀ gbà ó kọ èpístẹ́lì kan sí Kóríántúmúrì, pé bí yíò bá fi ara rẹ̀ lélẹ̀, kí òun ó lè pa pẹ̀lú idà rẹ̀, pé òun yíò dá ẹ̀mí àwọn ènìyàn nã sí. Ó sì ṣe tí àwọn ènìyan nã kò ronúpìwàdà kúrò nínú àìṣedẽdé wọn; àwọn ènìyàn Kóríántúmúrì sì ru ara wọn sókè ní ìbínú sí àwọn ènìyàn Ṣísì; àwọn ènìyàn Ṣísì sì rú ara wọn sókè ní ìbínú sí àwọn ènìyan Kóríántúmúri; nítorí èyí, àwọn ènìyàn Ṣísì sì gbé ogun tì àwọn ènìyàn Kóríántúmúrì. Nígbàtí Kóríántúmúrì sì ríi pé wọ́n fẹ́rẹ̀ borí òun ó tún sá níwájú àwọn ènìyàn Ṣísì. Ó sì ṣe tí ó dé ibi omi Ríplíákúmì, ní ìtúmọ̀sí èyítí ó jẹ́ títóbi, tàbí jù gbogbo wọn; nítorí èyí, nígbàtí wọ́n dé ibi omi yĩ wọ́n pàgọ́ wọn; Ṣísì pẹ̀lú pàgọ́ rẹ̀ nítòsí ibẹ̀; àti nitorinã ní ọjọ́ kejì wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ ogun jíjà. O sì ṣe ti wọn jà ogun tí ó gbóná gidigidi, nínú èyítí wọ́n tún ṣa Kóríántúmúrì lọ́gbẹ́, ó sì dákú nítorítí ó pádánù ẹ̀jẹ̀. Ó sì ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì sì dojúkọ àwọn egbẹ́ ọmọ ogun Ṣísì tí wọn bòrí wọn, tí wọ́n sì mú kí wọn ó sálọ níwájú wọn, wọ́n sì sálọ sí apá gũsù, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí ibìkan tí wọn npè ní Ógátì. Ó sì ṣe tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì sì pàgọ́ wọn síẹ̀bá òkè Rámà; òun sì ni òkè kannã níbití baba mi Mọ́mọ́nì gbé àwọn àkọsílẹ̀ pamọ́ sí Olúwa, tí wọ́n jẹ́ mímọ́. Ó sì ṣe tí wọ́n sì kó gbogbo àwọn ènìyàn nã jọ papọ̀ sí gbogbo orí ilẹ̀ nã, àwọn tí wọn kò ì pa àfi Étérì. O sì ṣe ti Étérì sì rí gbogbo ìṣe àwọn ènìyàn nã; ó sì ríi pé àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ ti Kóríántúmúrì kójọpọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì; àwọn ènìyàn ti ó sì jẹ́ ti Ṣísì kójọpọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ṣísì. Nítorí èyí, wọ́n fi ìwọ̀n ọdún mẹ́rin kó àwọn ènìyàn nã jọ, kí wọn ó lè rí gbogbo àwọn tí ó wà lórí ilẹ̀ nã, àti kí wọn ó lè gbà gbogbo agbára tí ó ṣẽṣe fún wọn láti rí gbà. Ó sì ṣe nígbàtí gbogbo wọn ti kójọ pọ̀ tán, olukúlùkù mọ́ ẹgbẹ ọmọ ogun èyítí ó bá fẹ́, pẹ̀lú àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn—àti àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé wọn sì dì ìhámóra ogun pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ogun, wọn sì ní àwọn àpáta, àti awo ìgbàyà, ati àwọn àwo àsíborí, wọ́n sì wọ̀ ẹ̀wù ogun—wọ́n sì jáde lọ ní ogun ọkan sí èkejì; wọ́n sì jà ní gbogbo ọjọ́ nã, kò sì sí ẹniti ó borí. Ó sì ṣe nígbàtí ó dí àṣálẹ́, ó rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì padà sí ibùdó wọn; lẹ́hìn tí wọ́n sì padà sí ibùdó wọn wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí hu wọn sì npohùnréré ẹkún fún àdánù àwọn tí a pa nínú àwọn ènìyàn wọn; ìgbè wọn, híhu wọn àti ìpohùnrere ẹkún wọn sì pọ̀ tóbẹ̃ tí wọn wọ̀ inú afẹ́fẹ́ lọ púpọ̀púpọ̀. Ó si ṣé ní ọjọ́ kejì wọ́n tún lọ jagun, ojọ́ nla èyítí ó burú sì ni ojọ́ nã; bíótilẹ̀ríbẹ̃, wọn kò borí, nígbàtí ó sì di àṣãlẹ́ wọ́n tún fi igbe wọn wọ inú afẹ́fẹ́, àti àwọn híhu wọn, àti àwọn ìkẹ́dùn ọkàn wọn, fún àdánù áwọn tí a pa nínú àwọn ènìyàn wọn. Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì tún kọ èpistélì kan sí Ṣísì, nínú èyítí ó ní oun kò fẹ́ kí ó wa sí ogun mọ́, ṣùgbọ́n kí ó gbà ìjọba nã, kí ó sì dá ẹ̀mí àwọn ènìyàn nã sí. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, Ẹ́mí Olúwa ti dẹ́kun láti bá wọn gbé, Sátánì sì ni agbara lórí ọkàn àwọn ènìyàn nã pátápátá; nítorítí wọ́n ti jọ̀wọ́ ara wọn sílẹ̀ fún síséle ọkàn wọn, àti ọkàn wọn tí o fọ́jú kí wọn ó lè parun; nítorí èyí wọn tún lọ sí ogun. Ó sì ṣe tí wọ́n jà ní gbogbo ọjọ nã, nígbàtí alẹ́ sì lẹ wọ́n sùn lórí àwọn idà wọn. Àti ni ọjọ́ tí ó tẹ̀lẽ wọn jà titi ilẹ̀ fi sú. Nígbàtí alẹ si lẹ́ wọn yó fún ìbínú, àní bí ẹnití ó yó pẹ̀lú wáìnì; wọ́n sì tún sùn lórí àwọn idà wọn. Àti ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lẽ wọ́n tún jà; nígbàtí alẹ́ sì lẹ́ gbogbo wọn ti ṣubú nípa idà, àfi àwọn méjìlélãdọ́ta nínú àwọn ènìyàn Kóríántúmúrì, àti àwọn mọ̀kàndínlãdọ́rin nínú àwọn ènìyàn Ṣísì. Ó sì ṣe ti wọn sùn lori àwọn idà wọn ni alẹ́ ọjọ́ nã, àti ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lẽ wọn tún jà, wọn sì jà pẹ̀lú gbogbo agbára wọn pẹ̀lú àwọn idà wọn ati pẹ̀lú àwọn àpáta wọn ní gbogbo ọjọ́ nã. Nígbàtí ó sì di àsálẹ́ àwọn mẹ́jìlélọ́gbọ̀n àwọn ènìyàn Ṣísì ní ó wà, àti àwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n àwọn ènìyàn Kóríántúmúrì. Ó sì ṣe tí wọn jẹun wọ́n sì sùn, wọ́n sì múrasílẹ̀ dè ikú ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lẽ. Wọ́n sì jẹ́ ènìyàn ti ó tóbi tí ó sì lágbára ni ti agbára ènìyàn. Ó sì ṣe tí wọ́n jà fún ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, wọ́n sì dákú nítorípé wọ́n pàdánù ẹ̀jẹ̀. Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ọmọ ogun Kóríántúmúrì ti tún gbà agbára tó tí wọn lè rìn, wọ́n Ṣetán láti sá fún ẹ̀mí ara wọn; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, Ṣísì dìde, àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì búra nínú ìbínu rẹ̀ pé òun yíò pa Kóríántúmúrì tàbí kí òun kú nípasẹ̀ idà. Nítorí èyí, ó sá tẹ̀lé wọn, ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lẽ ó sì bá wọn; wọ́n sì tún jà pẹ̀lú idà. Ó sì ṣe nígbàtí gbogbo wọn sì ti ṣubú nípa idà, àfi Kóríántúmúrì àti Ṣísì, ẹ kíyèsĩ Ṣísì dákú nítorípé ó ti pàdánù ẹ̀jẹ̀. Ó sì ṣe nígbàtí Kóríántúmúrì ti faratì idà rẹ̀, tí ó si simi díẹ̀, ó bẹ́ orí Ṣísì kúrò. Ó sì ṣe Lẹ́hìn tí ó ti bẹ́ orí Ṣísì, tí Ṣísì gbé ọwọ́ rè sókè ó sì ṣubúlulẹ̀; lẹ́hìn tí ó sì ti jà fún ẽmí, ó kù. Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì ṣubúlulẹ̀, ó sì rí bí i pé kò ní ẹ̀mí. Olúwa sì bá Étérì sọ̀rọ̀, ó sì wí fún un pe: Lọ jáde. Ó sì lọ jáde, o sì ríi pé àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa gbogbo ní a ti múṣẹ; ó sì pari àkọsílẹ̀ rẹ̀; (apá kán nínú ọgọ́run rẹ̀ ni èmi kò sì tĩ kọ) ó sì gbé wọn pamọ́ lọ́nà tí àwọn ènìyàn Límháì fi rí wọn. Nísisìyí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kẹ́hìn tí Étérì kọ ni ìwọ̀nyĩ: Bóyà Olúwa yíò sí mi nípò padà láìkú, tàbí kí èmi ó faradà ìfẹ́ Olúwa ní ti ara, kò jámọ́ nkankan, bí ó bá ri bẹ̃ tí a gbà mí là nínú ìjọba Olọ́run. Àmín. 1 Mórónì kọ̀wé fún ànfàní àwọn ara Lámánì—Àwọn ara Nífáì tí kò sẹ́ Krístì ni wọ́n pa. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa. NÍSISÌYÍ èmi, Mórónì, lẹ́hìn tí mó ti pari ṣíṣe ìkékúrú ọ̀rọ̀ nípa àwọn ènìyàn Járẹ́dì, mo lérò láti má kọ ohunkóhun mọ́, sùgbọn èmi kò ṣá tĩ kú; èmi kò sì fí ara mi hàn sí àwọn ara Lámánì ní ìbẹ̀rù pé wọn yíò pa mi run. Sì kíyèsĩ, àwọn ogun wọn gbóná lọ́pọ̀lọpọ̀ lãrín ara wọn; àti nítorí ìkórira wọn, wọ́n pa gbogbo ará Nífáì tí kò sẹ́ Krístì. Emí, Mórónì, kò sì ní sẹ́ Krístì; nítorí èyí, mo nrìn kiri sí ibikíbi tí mo bá lè lọ fún ãbò ẹ̀mí mi. Nítorí èyí, mo kọ ohun díẹ̀ sí i, ní ìyàtọ̀ sí ohun tí èmi rò láti ṣe tẹ́lẹ̀; nítorítí èmi lérò láti má kọ ohunkóhun mọ; ṣùgbọn mo kọ ohun díẹ̀ síi, pé bóyá wọ́n lè wúlò fún àwọn arákùnrin mi,àwọn ara Lámánì, ní ọjọ́ iwájú, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Olúwa. 2 Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn ara Nífáì méjìlá nnì ní agbára láti fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa. Àwọn ọ̀rọ́ Krístì, èyítíi ọ́ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀, àwọn méjìlá tí ó ti yàn, bí ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn— O sì fi orúkọ wọn pè wọ́n, wípé: Ẹyin yíò ké pè Bàbá ni orukọ mi, nínú àdúrà nlá; àti lẹ́hin tí ẹ̀yin bá ti ṣe eleyĩ ẹ̀yin yíò ní gbára pe ẹnití ẹ̀yin yíò gbe ọwọ yín le, ẹyin yíò fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún un; àti ní orúkọ mi ni ẹ̀yin yíò fi fún ni, nítorí báyĩ ni àwọn àpóstélì mi yíò ṣe. Nísisìyí Krístì sọ àwọn ọ̀rọ̀ yĩ fún wọn ní ìgbà tí ó kọ́kọ́ farahàn sí wọn; àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn kò sì gbọ́ ọ, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀hìn gbọ́ ọ; àti pe gbogbo iye àwọn tí wọ́n gbé ọwọ́ wọn lé, ni ó gbà Ẹ̀mí Mímọ́. 3 Àwọn àgbàgbà yàn àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni nípa gbígbé ọwọ́ lé wọn lórí. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Báyĩ ni ọ̀nà ti àwọn ọmọ ẹ̀hìn, àwọn tí a npè ní àwọn àgbàgbà ìjọ, ṣe yàn àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni— Lẹ́hìn tí wọ́n ti gbàdúrà sí Bàbá ní orukọ Krístì, wọ́n gbé ọwọ́ wọn lé wọn, wọ́n sì wípé: Ní orukọ Jésù Krístì, mọ̀ yàn ọ́ láti jẹ́ àlùfã (tàbí bí ó bá jẹ́ olùkọ́ni, mọ̀ yàn ọ́ l á t i j ẹ́ olùkọ́ni) láti wãsù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Krístì, nípa ìfaradà ìgbàgbọ́ nínú orukọ rẹ̀ títí dé òpin. Àmín. Àti ní ọ̀nà yĩ ni wọ́n yàn àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni, gẹ́gẹ́bí àwọn ẹ̀bùn àti àwọn ìpè tí Ọlọ́run pè ènìyàn; wọ́n sì yàn wọ́n nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, èyítí ó wà nínú wọn. 4 A ṣe àlàyé lórí bí àwọn àgbàgbà àti àwọn àlùfã ṣé nfi àkàrà àmì májẹ̀mú fún ni. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Ọ̀nà tí àwọn àgbàgbà wọn àti àwọn àlùfã wọn gbà nfi ara àti ẹ̀jẹ̀ Krístì fún ìjọ; wọ́n sì nfi fún ni ní ìbámu pẹ̀lú òfin Krístì; nítorí èyí, àwa mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀nà nã, alàgbà tabi àlùfã ní ó sì fifún ni— Wọ́n sì kúnlẹ̀ pẹ̀lú ìjọ, wọ́n sì gbàdúrà sí Bàbá ní orukọ Krístì, wípé: A! Olọ́run, Bàbá Ayérayé, àwa bẽrè lọ́wọ́ yín ní orúkọ Ọmọ yín, Jésù Krístì, pé kí ẹ bùkún kí ẹ sì yà àkàrà yĩ sí mímọ́ fún ọkàn gbogbo àwọn tí ó jẹ́ alábãpín nínú rẹ̀; láti lè jẹ ní ìrántí ara ti Ọmọ yín, kí wọ̀n ó sì jẹ̃rí sí yín, A! Ọlọ́run, Bàbá Ayéráyè, pé wọ́n ní ìfẹ́ láti gbà orúkọ ọmọ yín sórí wọn, wọn sì rántí rẹ̀ nígbàgbogbó, wọn sì npá òfin rẹ̀ mọ́ èyítí ó ti fi fun wọn, kí wọn ó lè ni Ẹ̀mi rẹ̀ pẹ̀lú wọn nígbàgbogbo. Àmín. 5 Wọn ṣe àlàyé nípa ọ̀nà tí a fí nfí wáìnì àmì májẹ̀mú fún ni. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Báyĩ ni ọ̀nà tí a fi nfí wáìnì fún ni—Ẹ kíyèsĩ, wọ́n mú àgo, wọ́n sì wípé: A! Olọ́run, Bàbá Ayérayé, àwa bẽrè lọ́wọ́ yín, ní orúkọ Ọmọ yín, Jésù Krístì, pé kí ẹ bùkún kí ẹ sì yà wáìnì yĩ sí mímọ́ fún ọkàn gbogbo àwọn tí ó mu nínú rẹ̀, láti lè ṣe é ní ìrántí ẹ̀jẹ̀ Ọmọ yín, èyítí a ta sílẹ̀ fún wọn; láti lè jẹ̃rí sí yín, A! Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, pé wọ́n nṣe ìrántí rẹ̀ nígbàgbogbo, kí wọn ó lè ní Ẹ̀mi rẹ̀ pẹ̀lú wọn. Àmín. 6 Àwọn ẹnití ó ronúpìwàdà ní a rìbọmi àti tí a nì ìdàpọ̀ pẹ̀lú—Àwọn ọmọ ìjọ́ tí ó ronúpìwàdà ni a dáríjì—A darí àwọn ìpàdé nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí èmi sọ̀rọ̀ nípa ìrìbọmi. Ẹ kíyèsĩ, àwọn àgbàgbà, àwọn àlùfã, àti àwọn olùkọ́ni ni a rìbọmi; a kò sì rì wọ́n bọmi bíkòṣepé wọ́n so èso èyítí ó yẹ tí o sì fi hàn pé ó tọ́ sí wọn. Bẹ̃ní wọn kò gbà kí ẹnikẹ́ni ó ṣe ìrìbọmi àfi bí wọ́n bá jáde wá pẹ̀lú ìròbìnújẹ́ àti ìrora ọkan àti ẹ̀mí ìròbínújé, tí wọ́n sì jẹrì sí ìjọ nã pé wọ́n ronúpìwàdà nítọ́tọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kò sì sí àwọn ènìyàn tí a gbà sínú ìrìbọmi bíkòṣepé wọ́n gbà orúkọ Krístì, tí wọn sì ni ìpinnu láti sìn ín títí dé òpin ayé wọn. Àti lẹ́hìn tí wọ́n sì ti gbà wọ́n sínú ìrìbọmi, tí a tún wọn ṣe tí a sì ti wẹ̀ wọ́n mọ́ nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, a kà wọ́n mọ́ àwọn ènìyàn ìjọ Krístì; a sì gbà orúkọ wọn, kí wọn ó lè máa rántí wọ́n àti kí wọn ó lè máa bọ́ wọn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti o dara, láti pa wọ́n mọ́ nínú ọ̀nà tí o tọ́, láti pa wọn mọ́ pẹ̀lú ìṣọ́ra nínú àdúrà títí, ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìtóye Krístì nìkan, ẹnití í ṣe olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wọn. Ìjọ́ nã a sì máa bá ara wọn péjọpọ̀ nígbàkũgbà, láti gbãwẹ̀ àti láti gbàdúrà, àti láti bá ara wọn sọ̀rọ̀ nípa àlãfíà ọkàn wọn. Wọn a sì máa bá ara wọn péjọpọ̀ ni gbàkũgbà láti jẹ́ nínú àkàrà àti wáìnì, ní ìrántí Jésù Olúwa. Wọ́n sì ṣọ́ra láti ríi pé kò sí aiṣedẽdé lãrín wọn; àti pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí tí ó nṣe àìṣedẽdé, tí àwọn ẹlẹ̃rí mẹ́ta nínú ìjọ, bá dá wọn lẹ́bi níwájú àwọn àgbàgbà, bí wọn kò bá sì ronúpìwàdà, tí wọn kò sì jẹ́wọ́, a ó pa orukọ wọn rẹ́, a kò sì ní kà wọ́n mọ́ àwọn ènìyàn Krístì. Sùgbọ́n nigbakũgbà tí wọ́n bá ronúpìwàdà, tí wọ́n sì tọrọ ìdáríjì, pẹ̀lú ìronújinlẹ̀, a dárí jì wọ́n. Ìjọ sì ní ó ndari àwọn ìpéjọpọ̀ wọn ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ Ẹ̀mí, àti nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́; nítorípé bí agbára Ẹ̀mí Mímọ́ bá ti darí wọn yálà láti wãsù ní, tabì láti gbani niyanju, tàbi láti gbàdúrà, tàbí láti bẹ̀bẹ̀, tàbi láti kọrin, àní bẹ̃ ní wọ́n ṣe. 7 A fún ni ní ìpè láti bọ́ sínú ìsimi Olúwa—Kí a má a gbàdúrà tọkàn-tọkàn—Ẹmí Krístì a máa jẹ́ kí ènìyàn ó mọ̀ rere yàtọ̀ sí búburú—Sátánì a máa tàn ènìyà láti sẹ́ Krístì àti làti ṣe búburú—Àwọn wòlĩ fi bíbọ̀ Krístì hàn—Nípa ìgbàgbọ́, iṣẹ́ ìyanu jẹ́ ṣíṣe àwọn Ángẹ́lì sì njíṣẹ́ ìránṣẹ́—Àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ nírètí fún ìyè àìnípẹ̀kun kí wọn ó sì rọ̀ mọ́ ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́. Ní ìwọ̀n ọdún 401–421 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Àti nísisìyí emí, Mórónì, kọ díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ bàbá mi Mọ́mọ́nì, èyítí ó sọ nípa ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́; nítorí ni ọ̀nà yĩ ni ó bá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀, bí ó ti nkọ́ wọn nínú sínágọ́gù èyítí wọ́n ti kọ́ fún ibi íjọ́sìn. Àti nísisìyí èmi, Mọ́mọ́nì, sọ fún yín, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́; àti pé nípasẹ̀ ọ́re-ọ̀fẹ́ Olọ́run tí i ṣe Bàbá, àti Olúwa wa Jésù Krístì, àti ìfẹ́-inú rẹ̀ mímọ́, nítorí ẹ̀bùn pípè rẹ̀ tí ó fi pè mí, ni a ṣe gbà fún mi láti bá yín sọ̀rọ̀ ní àkókò yĩ. Nítorí èyí, èmi yíò bá ẹ̀yin tí í ṣe ti ìjọ sọ̀rọ̀, tí í ṣe oníwàpẹ̀lẹ́ ènìyàn tí ntẹ̀lé Krístì, àti tí ó ti gbà ìrètì ti o to, nipa èyítí ẹyin yíò fi lè bọ́ sínú ìsimi Olúwa, láti ìgbà yí lọ títí dé ìgbà tí ẹ̀yin yíò simi pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run. Àti nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi, mo ṣe ìdájọ́ fún yin nípa àwọn ohun wọ̀nyí nítorí ìwàpẹ̀lẹ́ ti ẹ̀yín fi nbá àwọn ọmọ ènìyàn lò. Nitori èmi rànti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó sọ wípé nípa iṣẹ́ wọn ní ẹ̀yin ó mọ̀ wọ́n; nítorítí bí iṣẹ wọn bá jẹ́ rere, nígbànã ni àwọn nã yíò jẹ́ rere pẹ̀lú. Nítorí ẹ kíyèsĩ, Ọlọ́run ti sọ wípé ẹnití ó bá jẹ́ búburú kò lè ṣe èyítí ó jẹ rere; nítorí bí ó bá fún ní ní ẹ̀bún kan, tàbí kí ó gbàdúrà sí Ọlọ́run, afi bí ó bá ṣe é tọkàn-tọkàn kò jẹ èrè kan fúnun. Nítorí ẹ kíyèsĩ, à kò kã sí òdodo fún un. Nítorí ẹ kíyèsĩ, bí ènìyàn tí ó jẹ́ búburú bá fún ni ní ẹ̀bùn kan, a máa ṣeé pẹ̀lú ìkùnsínu; nítorí èyí a kà á fún un ní ọ̀nà kannã bí èyítí ó fi ọwọ́ mú ẹ̀bùn nã; nítorí èyí a kã sí ènìyàn búburú níwájú Ọlọ́run. Bákannã pẹ̀lú ni a kã sí búburú fún ènìyàn, bí ó bá gbàdúrà ṣùgbọ́n tí kò ṣe e tọkàn-tọkàn; bẹ̃ni, kò sì jẹ èrè kankan fún ún, nítorítí Ọlọ́run kò gbà irú ènìyàn bẹ̃. Nítorí èyí, ẹnití ó bá jẹ́ búburú kò lè ṣe èyítí í ṣe rere; bẹ̃ni kò lè fúnni ní ẹ̀bùn rere. Nítorí kíyèsĩ, orisun omi kíkorò kò lè sun omi dáradára jáde, bẹ̃ ni orísun omi dáradára kò lè sun omi kikorò jáde; nítorí èyí, ẹnití i bá í ṣe ìránṣẹ́ èṣù kò lè tẹ̀lé Krístì; bí ó bá sì tẹ̀lé Krístì kò lè jẹ́ iránṣẹ́ èṣù. Nítorí èyí, ohun gbogbo tí ó dára wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; èyítí ó sì jẹ́ búburú wá láti ọ̀dọ̀ èṣù; nítorítí èṣù jẹ ọ̀tá Ọlọ́run, a sì mã bá a jà títí, a sì mã pè, àti fà láti ṣẹ̀ àti láti ṣe èyítí ó burú títí. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èyítí íṣe ti Ọlọ́run a mã pè, àti fà láti ṣe rere títí; nítorí èyí, ohun gbogbo tí ó bá npè, tí ó sì nfà láti ṣe rere,àti láti ní ìfẹ́ Ọlọ́run, àti láti sìn ín, ni ìmísí Ọlọ́run. Nítorí èyí, ẹ kíyèsára, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, kí ẹ̀yin ó máṣe dájọ́ pé èyítí ó burú jẹ́ ti Ọlọ́run, tabi pé èyítí ó dára tí í sì í ṣe tí Ọlọ́run jẹ́ ti èṣù. Nitorí ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yín arákùnrin mi, a ti fún yín láti dájọ́, kí ẹ̀yin ó lè mọ́ rere yàtọ̀ sí búburú; ọ̀nà ṣíṣe ìdájọ́ sì jẹ́ èyítí ó ṣe kedere, kí ẹ̀yin ó lè mọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ pípé, gẹ́gẹ́bí ìmọ́lè ojúmọmọ ti yàtọ̀ sí òkùnkùn àṣálẹ́. Nítorí ẹ kíyèsĩ, a fún olukúlùkù ènìyàn ní Ẹ̀mí Krístì kí ó lè mọ̀ rere yàtọ̀ sí búburú; nítorí èyí, èmi yíò fihàn yin bí a ti í ṣè idájọ́; nítorítí ohun gbogbo tí í bá npè ènìyàn láti ṣe rére, àti láti yí ènìyàn lọ́kàn padà láti gbà Krístì gbọ́ ni a rán jáde nípa agbára àti ẹ̀bùn Krístì; nítorínã ẹ̀yin lè mọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ pípé pé ti Ọlọ́run ni íṣe. Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá yí ènìyàn lọ́kàn padà láti ṣe búburú, àti kí ó má gbà Krístì gbọ, kí ó sì sẹ́ ẹ, kí ó má sì sìn Olọ́run, nígbànã ni ẹ̀yin yíò mọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ pípé pé ti èṣù ní í ṣe; nìtoriti ní ọ̀nà yĩ ni èsù ngbà ṣiṣẹ́, nítorítí kò lè yí ẹnikẹ́ni lọ́kàn padà láti ṣe rere, rárá, àní ẹnikẹ́ni; tàbí àwọn ángẹ́lì rẹ̀; tàbí àwọn tí wọ́n fi ara wọn sí ábẹ́ rẹ̀. Àti nísisìyí, ẹyin arákùnrin mi, bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ ìmọ́lẹ̀ nípa èyítí ẹ̀yin ó ṣe ìdájọ́, ìmọ́lẹ̀ èyítí í ṣe ìmọ́lẹ̀ Krístì, kí ẹ ríi pé ẹ̀yin kò ṣe ìdájọ́ ní ọ̀nà tí kò tọ́; nitori irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe ní a ó sì ṣe fún yín pẹ̀lú. Nítorí èyí, mo bẹ̀ yin, ẹ̀yin arákùnrin, pé kí ẹ̀yin ó wákiri tọkàntara nínú ìmọ́lẹ̀ Krístì kí ẹ̀yin ó lè mọ̀ rere yàtọ̀ sí búburú; bí ẹ̀yin ó bá sì dì ohun gbogbo tí í ṣe rere mú, kí ẹ ma sì dáa lẹ́bi, dajúdajú ẹ̀yin yíò jẹ́ ọmọ Krístì. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, báwo ni ó ha ṣeéṣe fún yín láti lè dì ohun gbogbo tí í se rere mu? Àti nísisìyí èmi dé ibi ìgbàgbọ́ nnì, nípa èyítí mo sọ wípé èmi yíò sọ̀rọ̀; èmi yíò sì sọ fún yín níti ọ̀nà tí ẹ̀yin yíò gbà dì ohun gbogbo tí í ṣe rere mú. Nítorí ẹ kíyèsĩ, Olọ́run mọ̀ ohun gbogbo, nítorípé ó wà láti ayérayé dé ayérayé, kíyèsĩ, ó rán àwọn àngẹ́lì láti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ọmọ ènìyàn, láti mú kí bíbọ̀ Krístì di mímọ̀; àti pe nínú Krístì ní ohun rere gbogbo yíò dé. Ọlọ́run pẹ̀lú wí fún àwọn wòlĩ, láti ẹnu rẹ̀, pé Krístì yíò dé. Ẹ sì kíyèsĩ, onírúurú ọ̀nà ni ó fi fi àwọn ohun hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn, àwọn èyítí ó dara; gbogbo àwọn ohun tí ó sì dara ni o wá láti ọ̀dọ̀ Krístì; bíkòjẹ́bẹ̃ àwọn ènìyàn wà ní ìṣubú, kò sì sí ohun rere tí ó lè wá bá wọn. Nítorí èyí, nípà iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí àwọn ángẹ́lì nṣe, àti nipa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wa, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀sí fí ìgbàgbọ́ bá Krístì lò; àti nípa ìgbàgbọ́, wọn sì di ohun gbogbo tí í ṣe rere mú; báyĩ ní ó sì rí títí dì àkókò tí Krístì dé. Àti lẹ́hìn tí ó dé a gbà àwọn ènìyàn là pẹ̀lú nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; àti nípa ìgbàgbọ́, wọ́n di ọmọ Ọlọ́run. Bí o si ti daju pe Krístì wà lãyè ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn baba wa, wípé: Ohunkóhun tí ẹ̀yin bábẽrè lọ́wọ́ Bàbá ní orukọ mi, èyítí ó jẹ́ rere, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí ẹ sì gbàgbọ́ pe ẹ̀yin yio rí gbà, ẹ kíyèsĩ, á ó fifún yin. Nítorí èyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, njẹ́ àwọn isẹ́ ìyanu ha dópin nítorípé Krístì tí gòkè lọ sí ọ́run, àti tí ó sì ti jóko ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, láti gbà ẹ̀tọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ Bàbá èyítí ó ní nípa síṣe ãnú fún àwọn ọmọ ènìyan? Nítorítí ó ti ṣe ìdáhùn sí àwọn ohun tí ofin bẽrè fún, ó sì ti gbà gbogbo àwọn ti ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀; àwọn tí ó sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ yíò rọ̀ mọ́ ohun rere gbogbo; nítorí èyí a mã ṣe alágbàwí fún èyítí í ṣe tí àwọn ọmọ ènìyàn; ó sì ngbé nínú àwọn ọ̀run títí ayérayé. Àti nítoripé ó tí ṣe èyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, njẹ́ iṣẹ́ ìyanu ha ti dópin bi? Ẹ kíyèsĩ mo wí fún yín, Rárá; bẹ̃ni àwọn ángẹ́lì kò dáwọ́dúró nínú iṣẹ ìránṣẹ́ ṣíṣe fún àwọn ọmọ ènìyan. Nítorí ẹ kíyèsĩ, abẹ́ rẹ̀ ní wọ́n wà, láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ gẹ́gẹ́bí ó ti pàṣẹ, àti láti fi ara wọn hàn sí àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ púpọ̀ àti ọ̀kan ti ó dúróṣinṣin nínú ìwà-bí-Ọlọ́run. Ipò iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn sì wà láti pè àwọn ènìyan sí ìrònúpìwàdà, àti láti mú àwọn májẹ̀mú ṣẹ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ nípa ti àwọn májẹ̀mú Bàbá, èyítí ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ ènìyàn, láti pèsè ọ̀nà nã lãrín àwọn ọmọ ènìyàn, nípa sísọ ọ̀rọ̀ Krístì fún àwọn ohun èlò tí Olúwa yàn, láti lè jẹ̃rí nípa rẹ̀. Àti nípa ṣíṣe eleyĩ, Olúwa Ọlọ́run pèsè ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn yókù láti lè ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì, kí Ẹ̀mí Mímọ́ ó lè rí ãye nínú ọkan wọn, gẹ́gẹ́bí agbára rẹ̀; ní ọna yĩ sì ni Baba mú wọn ṣẹ, àwọn májẹ̀mú èyítí ó tí ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ ènìyàn. Krístì sì ti wípé: Bí ẹ̀yin ó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi ẹ̀yin yíò ní agbára láti ṣe ohunkóhun tí ó tọ́ nínú mi. Ó sì ti wípé: Ẹ ronúpìwàdà gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí a sì rì yín bọmi ní orúkọ mi, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi, kí a bã lè gbà yín là. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, bí ó bá rí bẹ̃ pé òtítọ́ ni àwọn ohun wọ̀nyí èyítí mo ti wí fún yín, Ọlọ́run yíò sì fi hàn sí yin, pẹ̀lú agbára àti ògo nlá ní ọjọ́ ìkẹhìn, pé òtítọ́ ni wọ́n í ṣe, bí wọn bá sì jẹ́ òtítọ́ njẹ́ ọjọ́ àwọn iṣẹ́ ìyanu ha ti dópin bí? Àbí àwọn ángẹ́lì ha ti síwọ́ láti fi ara han sí àwọn ọmọ ènìyàn bí? Àbí ó ha ti ká agbára Ẹ̀mí Mímọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn bí? Àbí yíò ha ṣe èyí bí, níwọ̀n ìgbà tí àkókò yíò wà, tàbí tí yíò kù ẹnìkanṣoṣo lórí rẹ̀ tí a ó gbàlà? Ẹ kíyèsĩ mó wí fún yín, Rárá; nítorítí nípa ìgbàgbọ́ ní àwọn iṣẹ́ ìyanu a máa ṣẹ̀; àti nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn ángẹ́lì a máa fì ara hàn àti tí wọn a máa jiṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn; nítorí èyí, bí àwọn ohun wọ̀nyí bá ti dáwọ́dúró ègbé ní fún àwọn ọmọ ènìyàn nítorítí èyí nnì rí bẹ̃ nítorí àìgbàgbọ́, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ asán. Nítorítí a kò lè gbà ẹnikẹ́ni là, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Krístì, àfí bí wọ́n bá ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; nítorí èyí, bí àwọn ohun wọ̀nyí bá ti dáwọ́dúró, nígbànã níìgbàgbọ́ ti dáwọ́dúró pẹ̀lú; ìpò búburú sì ni ènìyàn wà, nítorítí wọ́n wà bí èyítí a kò ṣe ìràpadà fún wọn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mí àyànfẹ́, mo ṣe ìdájọ́ nípa èyítí ó dára jù fún yín, nítorítí èmi ṣe ìdájọ́ pé ẹ̀yin ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì nitori ìwà tútù yín; nítorítí bí ẹ̀yin kò bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nígbànã ní kò tọ́ kí a kà yín mọ́ àwọn ènìyàn ìjọ rẹ̀. Àti pẹ̀lú, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, emí yíò bá yín sọ̀rọ̀ nípa ìrètí. Báwo ní ẹ̀yin ṣe lè ri ìgbàgbọ́ gbà, bíkòṣepé ẹ̀yin ní ìrètí? Kí sì ni ẹ̀yin yíò ní ìrètí fún? Ẹ́ kíyèsĩ mo wí fún yín pe ẹ̀yin yio ní ìrètí nípasẹ̀ ètùtù Krístì àti agbára àjínde rẹ̀, kí a gbé yín dìde sí ìyè tí kò nípẹ̀kun, èyítí ó sì rí bẹ̃ nítorí ìgbàgbọ́ yín nínú rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀. Nítorí èyí, kí ẹnikẹ́ni ó lè ní ìgbàgbọ́ ó níláti ní ìrètí; nítorí láìsí ìgbàgbọ́ kò lè sí ìrètí rárá. Àti pẹ̀lú, ẹ̀ kíyèsĩ mo wí fún yín pé òun kì yíò ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí, àfi bí ó bá jẹ́ oníwàtútù ènìyàn, àti onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ènìyàn. Bí ó bá rí bẹ̃, asán ni ìgbàgbọ́ àti ìrètí rẹ̀, nítorítí ẹnikẹ́ni kò jẹ́ ìtẹ́wógbà níwájú Ọlọ́run àfi oníwà tútù àti onírẹ̀lẹ́-ọkàn ènìyàn; bí ẹnikẹ́ni bá sì jẹ́ oníwàtútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn, tí ó sì jẹ́wọ́ nípa agbara Ẹ̀mí Mímọ́ pé Jésù ni Krístì nã, ó nílàti ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́; nítorítí bí kò bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ asán ní í ṣe; nítorí èyí ó níláti ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́. Ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ a máa mú sũrù, a sì máa ṣeun, kì í sì íṣe ìlara, kì í sì í fẹ̀, kì íwá ohun tí ara rẹ̀, a kĩ múu bínú, kĩ gbèrò ohun búburú, kì í sì í yọ̀ nínú àìṣedẽdé, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ nínú òtítọ́, a máa faradà ohun gbogbo, a máa gbà ohun gbogbo gbọ́, a máa reti ohun gbogbo, a sì máa fọkàn rán ohun gbogbo. Nítorí èyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, bí ẹ̀yin kò bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, òfo ni ẹ̀yin íṣe, nítorítí ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ kì í yẹ̀. Nítorí èyí, ẹ rọ̀mọ́ ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, èyítí ó tóbi jù ohun gbogbo, nítorítí ohun gbogbo gbodọ̀ kùnà— Ṣùgbọ́n ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ní ìfẹ́ Krístì tí kò ní àbàwọ́n, ó sì wà títí láe; ẹnikẹ́ni tí a bá sì rí ti ó ní i ní ọjọ́ ìkẹhìn, yíò dára fún un. Nítorí èyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ gbàdúrà sí Bàbá pẹ̀lú gbogbo agbára tí ó wà nínú yín, pé kí ìfẹ́ yì í ó kún inú yín, èyítí ó ti fi jínkí gbogbo àwọn tí wọn jẹ́ olùtẹ̀lé Ọmọ rẹ̀, Jésù Krístì; kí ẹ̀yin ó lè dì ọmọ Ọlọ́run; pé nígbàtí o bá fi ara hàn, a ó dàbí rẹ̀, nítorí àwa yio ríi àní bí ó ti ri; kí àwa ó lè ní ìrètí; kí Ọlọ́run ó lè sọ wá di mímọ́ àní bí òun ti mọ́. Àmín. 8 Ìrìbọmi àwọn ọmọdé jẹ́ ohun ìríra búburú—Àwọn ọmọdé wà lãyè nínú Krístì nítorí Etùtù nã—Ìgbàgbọ́, ìrònúpìwàdà, ìwà tútù àti ọkàn-ìrẹ̀lẹ̀, gbígbà Ẹ̀mí Mímọ́, àti ìfọkànrán dé opin ntọ́ni sí ìgbàlà. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Èpístélì bàbá mi Mọ́mọ́nì, èyítí ó kọ sí èmi, Mórónì; o sì kọ ọ́ sími ní kété lẹhìn ìpè mi sínú iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ní ọ̀nà yĩ ní ó sì fi kọ̀wé sí mi wípé: Àyànfẹ́ ọmọ mí, Mórónì, inú mi dùn lọ́pọ̀lọpọ̀ pé Olúwa rẹ Jésù Krístì ti fi ọ si ọkàn, ó sì ti pè ọ́ sínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, àti sínú iṣẹ́ mímọ́ rẹ̀. Mo nfi ọ si ọkan ní ìgbàgbogbo nínú àdúrà mi, tí mo sì ngbàdúrà títí sí Ọlọ́run Bàbá ní orukọ Ọmọ rẹ̀ Mímọ́, Jésù, pé òun, nípasẹ̀ ìwà rere àti ọ́re-ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìlópin, yíò pa ọ́ mọ́ nípa ìfọkànrán nínú ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀ titi dé òpin. Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo nbá ọ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó nbá mí nínújẹ́ gidigidi; nítorítí ó nbá mí nínújẹ́ pé àríyànjiyàn wà lãrín yín. Nítorí, bí èmi bá tí mọ̀ èyítí í ṣe òtítọ́, àríyànjiyàn ti wà lãrín yín nípa ìrìbọmi àwọn ọmọde yín. Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo fẹ́ kí ó ṣiṣẹ́ tọkàn-tọkàn, pé kí o mú àṣìṣe búburú yĩ kúrò lãrín yín; nítorípé, fún ìdí yĩ ni èmi ṣe kọ èpístélì yĩ. Ní kété lẹhìn tí mó tí gbọ́ nípa àwọn ohun yĩ nípa yín mó ṣe ìwádi lọdọ̀ Olúwa nípa ọ̀rọ̀ nã. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, wípé: Fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Krístì, Olùràpadà rẹ, Olúwa rẹ àti Ọlọ́run rẹ. Kíyèsĩ, èmi kò wá sínú ayé láti pè àwọn olódodo bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà; àwọn tí ara wọn le kì í wá oníṣègùn, bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá; nítorí èyí, àwọn ọmọdé wà ní aláìlẹ́ṣẹ̀, nítorítí wọn kò lè dẹ́ṣẹ̀; nítorí èyí ni a ṣe mú ègún Ádámù kúrò lórí wọn nítorí mi, pé kò lágbára lórí wọn; òfin ti ìkọlà ní a sì ti mú kúrò nítorí mi. Ní ọ̀nà yĩ sì ni Ẹ̀mí Mímọ́ fí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run hàn sí mi; nítorí èyí, ọmọ mi àyànfẹ́, èmi mọ̀ pé ẹ̀tàn ni èyí jẹ́ níwájú Ọlọ́run, pé kí ẹ̀yin ó ṣe ìrìbọmi fún àwọn ọmọdé. Kíyèsĩ mo wí fún ọ pé ohun yĩ ni ìwọ yíò kọ́ni—ìronúpìwàdà àti ìrìbọmi fún àwọn tí ó ti tó ójú bọ́ àti tí ó ti gbọ́n láti dẹ́ṣẹ̀; bẹ̃ni, kọ́ àwọn òbí pé wọ́n gbọdọ̀ ronupiwada kí a sì ṣe ìrìbọmi fun wọn, kí wọn ó sì rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ bí ọmọdé, a ó sì gbà gbogbo wọn là pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn— Àwọn ọmọde wọn kò níláti ṣe ìrònúpìwàdà, tabi ìrìbọmi. Kíyèsĩ ìrìbọmi wà fun ìrònúpìwàdà sí pípa àwọn òfin mọ́ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọdé wà lãyè nínú Krístì, àní láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé; bí kò bá rí bẹ̃, Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run tí i ṣe ojúṣãjú, àti Ọlọ́run tí í yípadà, àti tí í bẹ̀rù ènìyàn; nítorí àwọn ọmọde mélo ni ó ha ti kú láìṣe ìrìbọmi! Nítorí èyí, bí àwọn ọmọdé kò bá lè ní ìgbàlà láìṣe ìrìbọmi, èyi já sí pé wọ́n ti lọ sí ọ̀run àpãdì tí kò lópin. Kíyèsĩ mo wí fun ọ, pé ẹnití ó bà rò pé àwọn ọmọdé yẹ fún ìrìbọmi òun ni ó wà nínú ìkorò òrọ́ró àti ìdè aisedede; nítorítí kò ní èyítí í ṣe ìgbàgbọ́, ìrètí tàbí ìfẹ́ aláìlegbẹ́; nítorí èyí bí a bá ké e kúrò nígbàtí ó wà nínú èrò nnì, ọ̀run àpãdì ní yíò lọ. Nítorí búburú rẹ̀ pọ̀ jùlọ láti rò pé Olọ́run yíò gbà ọmọ kan là nítorí ìrìbọmi, tí òmíràn yíò sì ṣègbé nítorípé kò ní ìrìbọmi. Ègbé ni fun àwọn ẹniti yíò yí ọ̀nà Olúwa pó ní ọ̀nà yĩ, nítorítí wọn yíò ṣègbé àfi bí wọn bá ronúpìwàdà. Kíyèsĩ mo nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà, nítorípé mó ní àṣẹ láti ọwọ́ Ọlọ́run; èmi kò sì bẹ̀rù ohun tí ènìyàn lè ṣe; nítorí ìfẹ́ tí ó pé a máa lé ìbẹ̀rù jáde. Èmi si kún fún ìfẹ́ aláìlẹgbẹ́, èyítí í ṣe ìfẹ́ títí ayé; nítorí èyí, gbogbo ọmọdé ní ó jẹ́ bákannã sí mi; nítorí èyí, mo ní ìfẹ́ àwọn ọmọdé pẹ̀lú ìfẹ́ pípé; gbogbo wọn sì jẹ́ bákannã wọ́n sì jẹ́ alábãpín nínú ìgbàlà. Nítorípé mo mọ̀ pé Olọ́run kì í ṣe Ọlọ́run tí í ṣe ojúṣãjú, bẹ̃ní kì í ṣe ẹ̀dá tí í yípada ṣùgbọ́n ó wà ní àìyípadà láti gbogbo ayérayé dé gbogbo ayérayé. Àwọn ọmọdé kò lè ronúpìwàdà; nítorí èyí ohun búburú pupọ̀ jùlọ ni ó jẹ́ láti sẹ́ ọ̀pọ̀ ãnú Ọlọ́run tí ó wà lórí wọn, nítorítí wọ́n wà lãyè nínú rẹ̀ nítorí ãnú rẹ̀. Ẹnití ó bà sì sọ wípé àwọn ọmọdé yẹ fún ìrìbọmi ní ó sẹ́ ãnú Krístì, tí ó sì kà ètùtù rẹ̀ àti agbára ìràpadà rẹ̀ kún asán. Ègbé ni fún irú ẹni bẹ̃, nítorítí wọ́n wà nínú ewu ikú, ọrun àpãdì, àti oró àìnípẹ̀kún. Mo sọ ọ́ pẹ̀lú ìgboyà; Ọlọ́run ní ó pã laṣẹ fún mi. Fetí sílẹ̀ sí wọn àti kí ó ṣe àkíyèsí wọn, bíkòṣe bẹ̃ wọn yíò dúró ni ìtakò yín ní ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì. Nítorí kíyèsĩ pé gbogbo ọmọdé ni ó wà lãyè nínú Krístì, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà láìní òfin. Nítorítí agbara ìràpadà wà fún gbogbo àwọn tí kò ní òfin; nítorí èyí, ẹnití a kò bá dálẹ́bi, tàbí írú ẹnití kò sí lábẹ́ ìdálẹ́bi rárá, kò lè ronúpìwàdà; irú ẹni bẹ̃ ìrìbọmi kò jámọ́ nkan fún un— Sùgbọ́n ẹ̀tàn ní èyí níwájú Ọlọ́run, sísẹ́ ãnú Krístì, àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀, ó sì nfi ìgbẹ́kẹ̀lé sínú òkú iṣẹ́. Kíyèsĩ, ọmọ mi, èyí kò yẹ kí ó rí bẹ̃; nítorítí ìrònúpìwàdà wà fún ẹnití ó wà ní abẹ́ ìdálẹ́bi àti ní abẹ́ ègún òfin rírú. Eso àkọ́kọ́ ìrònúpìwàdà sì ni ìrìbọmi; ìrìbọmi a sì máa wá nípa ìgbàgbọ́ sí pípa àwọn òfin mọ́; pípa àwọn òfin mọ́ a sì máa mú ìdárijì ẹ̀ṣẹ̀ wá; Ìdárijì a sì máa mú ìwà-tútù wá, àti ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn; àti nítorí ìwàtútù àti ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn ìbẹ̀wò Ẹ̀mí Mímọ́ a máa wá, Olùtùnú èyítí fún ni ní ìrètí àti ìfẹ pípé, ìfẹ́ èyítí ífàyàrán ohun nípa ìtẹramọ́ nínú àdúrà gbígbà, títí òpin yíò dé, nígbàtí gbogbo ènìyàn mímọ́ yíò bá Ọlọ́run gbé. Kíyèsĩ, ọmọ mi, èmi yíò tún kọ̀wé sí ọ bí èmi kò bá tún tĩ lọ́ kọlũ àwọn ará Lámánì. Kíyèsĩ, ìgbéraga orílẹ̀-èdè yĩ, tàbí àwọn ènìyàn ará Nífáì tí jẹ́ ohun ìparun fún wọn àfi bí wọn bá ronúpìwàdà. Gbàdúrà fún wọn, ọmọ mi, kí ìrònúpìwàdà ó lè bá wọn. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ mo bẹ̀rù pé Ẹ̀mí Mímọ́ ti dẹ́kun láti bá wọn gbé; àti ní apá ilẹ̀ ibí yĩ wọn nwa ọ̀nà pẹ̀lú láti bì gbogbo agbára àti àṣẹ tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ṣubú; wọ́n sì nsẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́. Àti lẹ́hìn tí wọ́n ti kọ̀ ìmọ̀ nlá nã, ọmọ mi, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbé ní kánkán, sí ti ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀èyítí àwọn wòlĩ ti sọ, àti ọ̀rọ̀ Olùgbàlà wa fúnrarẹ̀ pẹ̀lú. Ó dìgbóṣe, ọmọ mi, títí èmi yíò kọ̀wé sí ọ, tàbí tún bá ọ pàdé. Àmín. Èpístélì kejì tí Mọ́mọ́nì sí ọmọ rẹ̀, Mórónì. Èyítí a kọ sí orí 9. 9 Àwọn ará Nífáì àti àwọn ara Lámánì di búburú, wọn sì fàsẹ́hìn—Wọn dá ara wọn lóró wọn sì pa ara wọn—Mọ́mọ́nì gbàdúrà kí ọ́re-ọ̀fẹ́ àti ire ó wà pẹ̀lú Mórónì títí láé. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ojọ́ Olúwa wa. Ọmọ mi àyànfẹ́, mo tún kọ̀wé sí ọ kí ìwọ ó lè mọ̀ pé mo sì wà lãyè; ṣùgbọ́n èmi yíò kọ nípa ohun tí o bani nínú jẹ́. Nítorí kíyèsĩ, mo ti jà ogun tí ó gbóná gidigidi pẹ̀lú àwọn ará Lámánì, nínú èyítí àwa kò ṣẹ́gun; Ákíantúsì sì ti ṣubú nípasẹ̀ idà, àti Lúrámù pẹ̀lú àti Ẹ́mrọ́mù; bẹ̃ni, àwa sì ti pàdánù púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn wa tí ó jẹ́ àṣàyàn. Àti nísisìyí kíyèsĩ, ọmọ mi, mo bẹ̀rù pé àwọn ará Lámánì yíò pa àwọn ènìyàn yĩ run; nítorítí wọn kò ronúpìwàdà, Sátánì sì nrú wọn sókè títí ní ìbínú sí ara wọn. Kíyèsĩ, èmi nṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn títí; nígbàtí mo bá sì sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìjáfáfá wọn a máa wárìrì wọn a sì máa bínú sí mi; nígbàtí èmi kò bá sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìjáfáfá wọn a sé ọkàn wọn le sí i; nítorí èyí, èmi bẹ̀rù pé Ẹ̀mi Olúwa ti dẹ́kun láti máa bá wọn gbé. Nítorítí wọn bínú gidigidi tóbẹ̃ tí mo wòye pé wọn kò ní bẹ̀rù fún ikú; wọ́n sì ti pàdánù ìfẹ́ tí wọ́n, ní ọ̀kan sí ẹlòmíràn; wọn a sì máa pòùngbẹ ẹ̀jẹ̀ àti ìgbẹ̀san títí. Àti nísisìyí, ọmọ mi àyànfẹ́, l’áìṣírò sísé le ọkàn wọn, jẹ́ kí àwa ó ṣiṣẹ́ tọkàn-tọkàn; nítorí bí àwa bá dẹ́kun láti máa ṣiṣẹ́, a ó gbà ìdálẹ́bi; nítorítí a ní iṣẹ́ láti ṣe nígbàtí a wà nínú àgọ ara yĩ, kí àwa ó lè ṣẹ́gun ẹnití ó jẹ́ ọ̀tá sí gbogbo ohun tí í ṣe òdodo, kí a sì fún ẹ̀mí wa ni ìsimi nínú ìjọba Olọ́run. Àti nísisìyí mo kọ̀wé díẹ̀ sí ọ nípa ìjìyà àwọn ènìyàn yĩ. Nítorí gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ tí mo ti gbà láti ọwọ́ Ámórónì, kíyèsĩ, àwọn ará Làmánì ní àwọn òndè tí ó pọ̀, àwọn tí wọn mú láti ilé-ìṣọ́ Ṣẹrísáhì; wọ́n sì jẹ́ ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé. Àwọn ọkọ àti àwọn bàbá àwọn obìnrin àti àwọn omọde nã ní wọ́n sì ti pa; wọ́n sì nbọ́ àwọn obìnrin nã pẹ̀lú ẹran ara àwọn ọkọ wọ̀n, àti àwọn ọmọ pẹ̀lú ẹran-ara àwọn bàbá wọn; wọn kòsì fún wọn ní omi, àfi díẹ̀. Àti l’áìṣírò àwọn ìwa ìríra púpọ̀ ti àwọn ara Lámánì yĩ, kò tàyọ tí àwọn ènìyàn wa ní Móríántúmù. Nítorí kíyèsĩ, wọn ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin àwọn ará Lámánì ní ìgbèkùn; àti lẹ́hìn tí wọ́n ti gbà èyítí ó ṣe ọ̀wọ́n jùlọ àti tí ó níye lórí jù ohun gbogbo, èyítí í ṣe wíwà ní mímọ́ àti ìwá-rere— Àti lẹ́hìn tí wọ́n ti ṣe eleyĩ, wọ́n pa wọn ní ọ̀nà tí ó rorò jùlọ, tí wọ́n ndá wọn lóró títí wọ́n fi kú; àti lẹ́hìn tí wọ́n ti ṣe eleyĩ, wọ́n a jẹ ẹran ara wọn bĩ ti àwọn ẹranko búburú, nítorí síséle ọkàn wọn; wọn á sì ṣe é gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí sí ìgboyà. A! ọmọ mí àyànfẹ́, báwo ni irú àwọn ènìyàn báyĩ, tí wọn kò ní ọ̀làjú— (Ọdún díẹ̀ ní ó sì ti kọjá lọ, láti ìgbàti wọ́n jẹ́ ọ̀làjú ènìyàn àti ẹnití ó wuni) Ṣùgbọ́n A! ọmọ mi, báwo ni irú àwọn ènìyàn báyĩ, tí ìdùnnú wọn wà nínú ìwà ìríra púpọ̀— Báwo ní àwa ó ṣe retí kí Ọlọ́run o dá ọwọ́ ìdájọ́ rẹ̀ sí wa duro? Kíyèsĩ, ọkàn mí nkígbe pé: Ègbé ni fun àwọn ènìyàn yĩ. Jáde wá nínú ìdájọ́, A! Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wọn pamọ́, àti ìwà íkà, àti àwọn ohun ìríra kúrò níwájú rẹ! Àti pẹ̀lú, ọmọ mi, àwọn opó púpọ̀ àti àwọn ọmọbìnrin wọn ni ó kù sẹ́hìn ní Ṣẹrísáhì; àti àwọn ohun ìpèsè tí àwọn ará Lámánì kò kó lọ, kíyèsĩ, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Sénífáì ti kó wọn lọ, wọ́n sì fi wọ́n sílẹ̀ láti máa rìn kiri lọ sí ibikíbi tí wọn lè lọ láti wá oúnjẹ kiri; àwọn arugbó obìnrin púpò ní ãrẹ̀ mú ní ọ̀nà tí wọ́n sì kú. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó wà lọ́dọ̀ mi sì ṣe àìlera; àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì sì wà lãrín èmi àti Ṣẹ́rísáhì; gbogbo àwọn tí ó sì ti sá lọ sínu ẹgbẹ́ ọmọ ogun Áárọ́nì ní ó ti bọ́ sọ́wọ́ ìrorò búburú wọn. A! wọ́n ti sọ àwọn ènìyàn mi di búburú tó! Wọ́n wà láìní ètò àti láìní ãnú. Kíyèsĩ, ènìyàn lásán ni mo jẹ́, agbara ènìyàn nìkan ni èmi sì ní, èmi kò sì lè pàṣẹ mọ́. Wọ́n sì ti di alágbára nínú ìwa àrekérekè wọn; wọ́n sì rorò bákannã, wọn kò sì dá ènìkan sí, ní arúgbó ni tàbí ọmọdé; wọ́n sì ndùnnú sí ohun gbogbo àfi èyítí ó jẹ́ rere; ìjìyà àwọn obìnrin wa àti àwọn ọmọ wa lórí ilẹ̀ yĩ sì tayọ ohun gbogbo, bẹ̃ni, ahọ́n kò lè sọ, bẹ̃ni a kò lè kọ ọ́. Àti nísisìyí, ọmọ mi, èmi kò sọ nípa ohun ìṣẹ̀lẹ̀ búburú yĩ mọ. Kíyèsĩ, ìwọ mọ̀ ìwà búburú àwọn ènìyàn yĩ; ìwọ mọ̀ pé wọn kò ní òfin, àyà wọn sì le rékọjá; ìwà búburú wọn sì tayọ tí àwọn ará Lámánì. Kíyèsĩ, ọmọ mi, èmi kò lè sọ̀rọ̀ wọn ní réré fún Ọlọ́run kí ó má bã bá mi jà. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ọmọ mi, èmi sọrọ rẹ ní rere fun Ọlọ́run, èmi sì ní ìgbẹ́kẹ̀lè nínú Krístì pé a ó gbà ọ́ là; mo sì gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó dá ẹ̀mí rẹ sí, láti lè rí pípadà àwọn ènìyàn rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, tàbí ìparun wọn pátápátá; nítorítí mo mọ̀ pé wọ́n níláti parun àfi bí wọ́n bá ronúpìwàdà kí wọ́n sì padà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí wọ́n bá sì parun yíò rí bĩ ti àwọn ará Járẹ́dì, nítorí ìfẹ inú ọkàn wọn láti mã lépa ìtàjẹ̀sílẹ́ àti ìgbẹ̀san. Bí ó bá sì rí bẹ̃ tí wọ́n parun, àwa mọ̀ pé púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin wa ni o ti fi wá sílẹ̀ láti lọ darapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní yíò sì fi wá sílẹ̀ síi láti lọ darapọ̀ mọ́ wọn; nítorí èyí, kọ àwọn ohun díẹ̀, bía bá sì dá ọ sí tí èmi sì parun tí èmi kò sì rí ọ mọ́; ṣùgbọ́n emi ní ìdánilójú pé èmi yíò rí ọ ní àìpẹ́; nítorí èmi ní àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ tí èmi fẹ́ láti gbé fún ọ. Ọmọ mi, jẹ olótĩtọ́ nínú Krístì; njẹ́ kí àwọn ohun tí èmi ti kọ ó máṣe bà ọ́ nínú jẹ́, kí ó sì rìn ọ́ mọ́lẹ̀ dé ojú ikú; ṣùgbọ́n kí Krístì ó gbé ọ sókè, àti kí ìjìyà àti ikú rẹ̀, àti fifi ara rẹ̀ hàn sí àwọn baba wa, àti ãnú àti irọ́jú rẹ̀, àti ìrètí fún ògo rẹ̀ àti fún ìyè àìnípẹ̀kun, wọ̀ ínú ọkàn rẹ lọ títí láé. Àti kí ọ́re-òfẹ́ Ọlọ́run Baba, ẹnití ìtẹ́ rẹ̀ ga sókè nínú àwọn ọ̀run, àti Olúwa wa Jésù Krístì, ẹnití ó jóko ní ọwọ́ ọ̀tún agbára rẹ̀, títí ohun gbogbo yíò wà lábẹ́ àṣẹ rẹ̀, kí ó wà, kí ó sì máa bá ọ gbé títí láé. Àmín. 10 Ẹ̀rí nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì wá nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́—Àwọn ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí ni a fifún àwọn olótitọ́ ènìyàn—Àwọn ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí a máa bá ìgbàgbọ́ rìn—Ọ̀rọ̀ Mórónì jáde wá láti inú erupẹ̀—Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, kí a sì sọ yín di pípé nínú rẹ̀, kí ẹ̀yin ó sì sọ ẹ̀mí yín di mímọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa. Nísisìyí èmi, Mórónì, kọ àwọn ohun díẹ̀ bí ó ti dára lójú mi; èmi sì kọ̀we sí àwọn arákùnrin mi, àwọn ara Lámánì; èmi sì fẹ́ kí wọn ó mọ̀ pé irínwó àti ogún ọdún ti kọjá láti ìgbà tí a ti fúnni ní àmì nípa bíbọ̀ Krístì. Èmí sì fi èdìdí dì àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí, lẹhìn tí mo ti sọ̀rọ̀ díẹ̀ láti gbà yín níyànjú. Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀mi yíò rọ̀ yín pé nígbàtí ẹ̀yin yio bá kà àwọn ohun wọ̀nyí, bí ó bá jẹ́ ọgbọ́n nínú Ọlọ́run pé kí ẹ̀yin ó kà wọ́n, pé ẹyin ó rántí bí Olúwa tí ní ãnu tó sí àwọn ọmọ ènìyàn, láti igbà dídá Ádámù àní títí dé ìgbà tí ẹ̀yin yíò rí àwọn ohun wọ̀nyí gbà, kí ẹ sì ṣe àsarò lórí rẹ̀ nínú ọkàn yín. Àti nígbatí ẹ̀yin yíò sì rí àwọn ohun wọ̀nyí gbà, èmi gbà yín níyànjú pé kí ẹ bẽrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, ní orukọ Krístí, bí àwọn ohun wọ̀nyí kò bá íṣe òtítọ́; bí ẹ̀yin yíò bá sì bẽrè, tọkàn-tọkàn pẹ̀lú gbogbo ìfẹ́ inú yín, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì, yíò fi òtítọ́ inú rẹ̀ hàn sí yín, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ̀. Àti nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin lé mọ̀ òtítọ́ ohun gbogbo. Ohunkóhun tí ó bá sì jẹ́ rere jẹ èyítí ó tọ́ àti tí í ṣe òtítọ́; nítorí èyí, kò sì ohun tí ó jẹ rere tí í sẹ Krístì, ṣùgbọ́n a máa jẹ́wọ́ pé òun ni. Ẹ̀yin sì lè mọ̀ pé òun ni, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́; nítorí èyí èmi yíò gbà yín níyànjú, pé kí ẹ máṣe sẹ́ agbára Ọlọ́run; nítorítí ó nṣiṣẹ́ nípa agbara, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ènìyàn, ọ̀kan nã ní òní àti ní ọ̀la, àti títí láé. Àti pẹ̀lú, mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé kí ẹ máṣe sẹ́ àwọn ẹ̀bùn Ọ́lọ́run, nítorítí wọ́n pọ̀; wọ́n sì wá láti ọwọ́ Ọlọ́run kannã. Óríṣiríṣi ọ̀nà sì ni a ngbà fi fún ni ní àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí; ṣùgbọ́n Ọlọ́run kannã ní ẹni tí nṣe ohun gbogbo nínú ohun gbogbo; wọn a sì máa fifún ni nípa ìfihàn Ẹmi Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn, láti ṣe ànfàní fún wọn. Nítorí ẹ kíyèsĩ, nípa Ẹ̀mi Ọlọ́run a fi fún ẹnìkan láti kọ́ni ní ọ̀rọ̀ ọgbọ́n; Àti fún ẹlòmíràn, láti kọ́ni ní ọ̀rọ̀ ìmọ̀ nípa Ẹ̀mí kánnã; Àti fún ẹlòmíràn, ìgbàgbọ́ nlá èyítí ó pọ̀; àti fún ẹlòmíràn, ẹ̀bùn ìmúláradá nípa Ẹ̀mí kannã; Àti pẹ̀lú, fún ẹlòmíràn, láti lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu nlá; Àti pẹ̀lú, fún ẹlòmíràn, láti lè sọtẹ́lẹ̀ nípa ohun gbogbo; Àti pẹ̀lú, fún ẹlòmíràn, láti máa rí àwọn ángẹ́lì àti ẹ̀mí tí njíṣẹ́ iranṣẹ; Àti pẹ̀lú, fún ẹlòmíràn, onírúurú èdè; Àti pẹ̀lú, fún ẹlòmíràn, ìtumọ̀ èdè àti onírúurú èdè. Gbogbo àwọn ẹ̀bùn yĩ sì wá nípa Ẹ̀mí Krístì; a sì nfi wọ́n fún olukúlùkù; gẹ́gẹ́bí ó ti wù ú. Èmi sì gbà yín níyànjú, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, pé kí ẹ rántí pé láti ọwọ́ Krístì ni gbogbo ẹbun rere ti wá. Èmi sì gbà yín níyànjú, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, pé kí ẹ rántí pé òun ni ọ̀kan nã ní àná, ní òní, àti títí láé, àti pé gbogbo àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tí èmi ti sọ nípa wọn, èyítí í ṣe ti ẹ̀mí, kò lè parẹ́, àní ní ìwọ̀n ìgbà tí ayé yíò wà, àfí nípa àìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ènìyàn nìkan. Nítorí èyí, ó yẹ kí ìgbàgbọ́ ó wà; bí ó bá sì yẹ kí ìgbàgbọ́ ó wà ìrètí níláti wà pẹ̀lú; bí ó bà sì yẹ kí ìrètí ówàìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ nílátiwà. Àti pé àfi bí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ a kò lè gbà yín là nínú ìjọba Ọlọ́run; bẹ̃ni a kò lè gbà yín là nínú ìjọba Ọlọ́run bí ẹ kò bá ní ìgbagbọ́; bẹ̃ni a kò lè gbà yín la bí ẹ kò bá ní ìrètí. Bí ẹ̀yin kò bá sì ní ìrètí ó di dandan ki ẹ̀yin wà láìnírètí, àìnírètí sì nwa nítorí àìṣedẽdé. Krístì sì sọ nítọ́tọ́ fún àwọn baba wa pé: Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ ẹ̀yin yíò ṣe ohun gbogbo tí ó tọ́ sí mi. Àti nísisìyí èmi nbá gbogbo ìkangun ayé sọ̀rọ̀—pé bí ọjọ́ nã bá dé tí agbara àti àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run yíò dẹ́kun, yíò rí bẹ̃ nítorí àìgbàgbọ́. Ègbé sì ní fún àwọn ọmọ ènìyàn bí ó bá rí báyĩ; nítorítí kì yíò sì ẹnikẹ́ni tí nṣe rere lãrín yín, rárá kòsí ẹnìkan. Nítorí bí ẹnikan bá wà lãrín yin tí nṣe rere, yíò ṣiṣẹ́ nípa agbára àti àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run. Ègbé sì ni fún àwọn tí yíò mú àwọn ohun wọ̀nyí kúrò tí wọn sì kú, nítorítí wọ́n kú nínú ẹṣẹ wọn, a kò sì lè gbà wọ́n là nínú ìjọba Ọlọ́run; èmi sì nsọ ọ́ gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì; èmi kò sì purọ́. Mo sì gbà yín níyànjú láti ranti àwọn ohun wọ̀nyí; nítorítí àkókò nã yíò dé kánkán tí ẹ̀yin yíò mọ̀ pé èmi kò purọ́, nítorítí ẹ̀yin ó rí mi níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run; Olúwa Ọlọ́run yíò sì wí fún yín pe: Njẹ èmi kò ha kéde ọ̀rọ̀ mi fun yín bí, àwọn tí ọkùnrin yĩ kọ, bí ẹnití nkígbe jáde láti ipò òkú, bẹ̃ni, àní bí ẹnití nsọ̀rọ̀ jáde wá láti inú erùpẹ̀? Mo sọ àwọn ohun wọ̀nyí sí ti ìmúṣẹ àwọn ìsọtẹ́lẹ̀. Ẹ sì kíyèsĩ, wọn yíò jáde lọ láti ẹnu Ọlọ́run tí ó wà títí ayé; ọ̀rọ̀ rẹ̀ yíò sì kọ jáde láti ìran dé ìran. Ọlọ́run yíò sì fi hàn sí ọ, pé èyítí èmi ti kọ jẹ́ òtítọ́. Àti pẹ̀lú èmi yíò gbà yín níyànjú pé kí ẹ wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, kí ẹ sì dì ẹ̀bùn gbogbo èyí tí í ṣe rere mú, kí ẹ má sì ṣe fi ọwọ́ kàn ẹ̀bùn búburú, tàbí ohun àìmọ́. Kí o sì jí, kí o sì dìde kúrò nínú erùpẹ̀, A! Jerúsálẹ́mù; bẹ̃ni, kí o sì gbé ẹ̀wù arẹwà rẹ wọ̀, A! ọmọbìnrin Síónì; kí o sì fí agbára kún àwọn àgọ́ rẹ kí o sì fẹ̀ ìpínlẹ̀ rẹ títí láé kí á má sì ṣe dàmú rẹ mọ́, kí àwọn májẹ̀mú Bàbá Ayérayé èyítí ó tí dá pẹ̀lú rẹ, A! ìdílè Isráẹ́lì ó lè di mìmúṣẹ. Bẹ̃ni, ẹ wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, kí a sì sọ yín di pípé nínú rẹ̀, kí ẹ sì sẹ́ ara yín ní ti gbogbo àìwàbí-Ọlọ́run; bí ẹ̀yin bá sì sẹ́ ara yín ní t i gbogbo àìwà-bíỌlọ́run, àti kí ẹ sì fẹ Ọlọ́run pẹ̀lu gbogbo agbara, iyè àti ipá yín, nígbànã ni ọ́re-ọ̀fẹ́ rẹ̀ sì tó fún yín, pé nípa ọ́re-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ẹ̀yin lè di pípé nínú Krístì; àti nípa ọ́re-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run bí ẹ̀yin bá di pípé nínú Krístì, ẹ̀yin kò lè sẹ́ agbára Ọlọ́run. Àti pẹ̀lú, bí ẹ̀yín bá jẹ́ pípé nínú Krístì nípa ọ́re-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí ẹ kò sì sẹ́ agbara rẹ̀, nígbànã ni a ó sọ yín di mímọ́ nínú Krístì nípa ọ́re-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, nípasẹ̀ títa ẹ̀jẹ̀ Krístì sílẹ̀, èyítí ó wà nínú májẹ̀mú ti Bàbá sí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀yin ó lè di mímọ́, láìní àbàwọ́n. Àti nísisìyí mo kí yín, ó dìgbóṣe. Èmí yíò lọ sì párádísè Ọlọ́run láìpẹ́ yĩ, títí ìgbàtí ẹ̀mí àti ara mi yíò tún dàpọ̀, tí á ó sì mú mi jáde pẹ̀lú ayọ̀ ìṣẹ́gun nínú òfúrufú, láti pàdé yín níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ aláyọ̀ ti Jèhófàh nlá, Onídàjọ́ Ayérayé tí ãye àti òkú. Àmín. ÌPARÍ ATỌ́KA SÍ ÌWÉ TI MỌ́MỌ́NÌ