Sí Ọmọkùnrin Nóà Ádámù, Ṣétì, Énọ́sì, Kénánì, Máháláléélì, Jérédì, Hénókì, Mètúsẹ́là, Lámékì, Nóà Àwọn ọmọ Nóà, Ṣémù, Ámù àti Jáfétì Àwọn ọmọ Jáfétì Gómérì, Mágógù, Mádà Jáfánì, Túbálì, Méṣékì, Tírásì Àwọn ọmọ Gómérì Áṣíkénásì, Bífátì, Tógárímà Àwọn ọmọ Jáfánì Èlíṣà, Tárísísì, Kítímù, àti Dódánímù Àwọn ọmọ Ámù Kúṣì, Ṣébà, Mísíráímù, Pútì, àti Kénánì Àwọn ọmọ Kúṣì Ṣébà Háfílà, Ṣébítà, Rámà, àti Ṣábítékà, Àwọn ọmọ Rámà Ṣébà àti Dédánì Kúṣì ni baba Nímíródù Ẹni tí ó dàgbà tí ó sì jẹ́ jagunjagun alágbára lórí ilẹ̀ ayé Mísíráímù ni baba Lúdímù, Ánámímù, Léhábímù, Náfítúhímù, Pátírísímù, Kásiliúhímù, àti Káfitórímù Kénánì ni baba Ṣídónì àkọ́bí Rẹ̀, àti ti àwọn ará Hítì, Àwọn ará Jébúsì, àwọn ará Ámórì, àwọn ará Gírígásì Àwọn Hífì, àwọn ará Áríkì, àwọn ará Hamati-Ṣínì, Àwọn ará Árífádù, àwọn ará, Ṣémárì, àwọn ará Hámátì Àwọn ọmọ Ṣémù Élámù Ásúrì, Árífákásádì, Lúdì àti Árámù Àwọn ará Árámù Usì Húlì, Gétérì, àti Méṣékì Árífákásádì sì jẹ́ Baba Ṣélà, àti Ṣélà sì jẹ́ Baba Ébérì A bí àwọn ọmọ méjì fún Ébérì Orúkọ ọ̀kan ni Pélégì, nítorí ní àkókò tirẹ̀ a pín ayé orúkọ ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ ọkùnrin a sì máa jẹ́ Jókítanì Jókítanì sì jẹ́ Baba fún Hímódádì, Ṣéléfì, Hásárímáfétì, Jérà Hádórámì, Úsálì, àti Díkílà Ébálì, Ábímáélì, Ṣébà Ófírì, Háfílà, àti Jóbábù Gbogbo àwọn wọ̀nyí sì jẹ́ àwọn ọmọ Jókítanì Ṣémù, Árífákásádì, Sẹ́bà, Ébérì, Pélégì Réù, Ṣérúgì, Náhórì, Térà Àti Ábúrámù Àwọn ọmọ Ábúráhámù Ísáákì àti Íṣímáẹ́lì Èyí ni àwọn ọmọ náà Nébáíótì àkọ́bí Íṣímáẹ́lì Kédárì, Ádíbélì, Míbísámù, Míṣímà, Dúmà, Másà, Hádádì, Témà, Jétúrì, Náfísì, àti Kédámù Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Íṣímáẹ́lì Àwọn ọmọ Kétúrà, obìnrin Ábúráhámù Símíránì, Jókíṣánì Médánì, Mídíánì Iṣíbákì àti Ṣúà Àwọn ọmọ Jókísánì Ṣébà àti Dédánì Ọmọ Mídíánì Éfà Hénókì, Éférì, Ábídà àti Élídà Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Kétúrà Ábúráhámù sì jẹ́ baba Ísáákì Àwọn ọmọ Ísáákì Ísọ̀ àti Ísírẹ́lì Àwọn ọmọ Ísọ̀ Élífásì, Réuélì, Jéúsì, Jálámù, àti Kórà Àwọn ọmọ Élífásì Témánì, Ómárì, Ṣéfì, Gátamù àti Kénásì làti Tímánà Ámálékì Àwọn ọmọ Réúélì Náhátì, Ṣérà, Ṣámà àti Mísà Àwọn ọmọ Ṣéírì Lótanì, Ṣóbálì, Ṣíbéónì, Ánà, Díṣónì, Ésárì àti Dísánì Àwọn ọmọ Lótanì Hórì àti Hómámù Tímínà sì jẹ́ arábìnrin Lótanì Àwọn ọmọ Ṣóbálì Álíánì, Mánánátì, Ébálì, Ṣéfì àti Ónámù Àwọn ọmọ Ṣíbéónì Áíyà àti Ánà Àwọn ọmọ Ánà Díṣónì Àwọn ọmọ Díṣónì Hémídánì, Éṣébánì, Ítíránì, àti Kéránì Àwọn ọmọ Èsérì Bílíhánì, Ṣáfánì àti Jákánì Àwọn ọmọ Díṣánì Húsì àti Áránì Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Édómù, kí ó tó di wí pé àwọn ọba ará Ísírẹ́lì kán jẹ Bélà ọmọ Béórì, ẹni tí orúkọ ìlú Rẹ̀ a máa jẹ́ Díníhábà Nígbà tí Bélà kú, Jóbábù ọmọ Ṣérà láti Bósírà jẹ ọba dípò Rẹ̀ Nígbà tí Jóbábù sì kú, Húṣámù láti ilẹ̀ àwọn ará Témánì sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀ Nígbà tí Húṣámù sì kú, Hádádì ọmọ Bédádì, ẹni tí ó kọlu Mídíánì ní agbégbé Móábù, ó sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀ Orúkọ ìlú Rẹ̀ sì ni Áfítì Nígbà tí Hádádì sì kú, Ṣámílà láti Másírékà, ó sì jọba ní ipò Rẹ̀ Nígbà tí Ṣámílà sì kú, Ṣáúlì láti Réhóbótì lórí odò sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀ Nígbà tí Ṣáúlì sì kú, Báli-hánánì, ọmọ Ákíbórì sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀ Nígbà tí Báli-hánánì sì kú, Hádádì sì di ọba nípò Rẹ̀ Orúkọ ìlú Rẹ̀ sì ni Páì àti orúkọ ìyàwó sì ni Méhélábélì ọmọbìnrin Métírédì, ọmọbìnrin Mésíhábù Hádádì sì kú pẹ̀lú Àwọn olórí Édómù ni Tímínà, Álífà, Jététì Óhólíbámà, Élà, Pínónì Kénásì, Témánì, Mísárì, Mágádíẹ́lì àti Ìrámù Àwọn wọ̀nyí ni Olórí Édómù Ṣọ́ọ̀lù Gba Ẹ̀mí Ara Rẹ̀ Nísinsin yìí, àwọn ará Fílístínì dojú ìjà kọ Ísírẹ́lì, Àwọn ará ísírélì sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí ọri òkè Gílíbóà Àwọn ará Fílístínì sí lépa Sáúlù gidigidi àti àwọn ọmọ Rẹ̀ Wọ́n sì pa àwọn ọmọ Rẹ̀ Jónátanì, Ábínádábù àti Málíkíṣúà Ìjà náà sì ń gbóná síi yí Sáúlù ká Nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ pé, Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é Bẹ́ẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù mú idà tirẹ̀ ó sì subú lé e Nígbà tí agbé-ìhámọ́ra rí pé Ṣọ́ọ̀lù ti kú, òhun pẹ̀lú subú lórí idà tirẹ̀, ó sì kú Bẹ́ẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ Rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú gbogbo ilé Rẹ̀ sì kú lápapọ̀ Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rí wí pé àwọn ọmọ ogun ti sálọ àti pé Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ Rẹ̀ ti kú wọ́n kọ àwọn ìlú wọn sílẹ̀, wọ́n sì sálọ Àwọn ará Fílístínì wá, wọ́n sì gba ipò wọn Ní ọjọ́ kejì, Nígbà tí àwọn ará Fílístínì wá láti kó okú, wọ́n rí Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ Rẹ̀ tí wọ́n ṣubú sórí òkè Gílíbóà Wọ́n bọ́ ọ láọ , wọ́n sì gbé orí Rẹ̀ àti ìhámọ́ra Rẹ̀ Wọ́n sì rán ìránṣẹ́ lọ kákiri ilẹ̀ Àwọn ará Fílístínì láti kéde ìròyìn náà láàrin àwọn òrìṣà wọn àti àwọn ènìyàn wọn Wọ́n gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ sí inú ilé tí wọ́n kọ́ fún òrìsà wọn, wọ́n sì fi orí Rẹ̀ kọ́ sí inú ilé Dágónì Nígbà tí gbogbo àwọn olùgbé Jábésì Gíléádì gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ará Fílístínì ṣe fún Ṣọ́ọ̀lù, Gbogbo àwọn akọni ọkùnrin wọn lọ láti mú àwọn ará Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ Rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Jábésì Nígbà náà, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi ńlá ní Jábésì, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ méje Ṣọ́ọ̀lù kú nítorí kò se òtítọ́ sí Olúwa Kò pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ pẹ̀lú, ó tọ abókúsọ̀rọ̀ lọ fún ìtọ́sọ́nà Kò sì bèrè lọ́wọ́ Olúwa , bẹ́ẹ̀ ni Olúwa pa á, Ó sì yí ìjọba náà padà sọ́dọ̀ Dáfídì ọmọ Jésè Dáfídì Di Ọba Lórí Ísírẹ́lì Gbogbo àwọn Ísírẹ́lì kó ara wọn jọ pọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì wọ́n sì wí pé, Àwa ni ẹran ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ Ní àtijọ́, kódà nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù jẹ ọba, ìwọ ni ẹni tí ó darí Ísírẹ́lì ní ojú ogun wọn Olúwa Ọlọ́run rẹ sì wí fún ọ pé, Ìwọ yóò sì jẹ́ olùsọ́ àgùntàn fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún wọn   Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dáfídì ni Hébúrónì Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hébúrónì níwájú Olúwa , wọ́n sì fi àmìn òróró yan Dáfídì ọba lórí Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí láti ọ̀dọ̀ Ṣámúẹ́lì Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde lọ sí Jérúsálẹ́mù Àwọn ara Jébúsì ẹni tí ń gbé níbẹ̀ Wí fún Dáfídì pé, ìwọ kò sì gbọdọ̀ rí nínú ibẹ̀ Bí ó ti lẹ̀jẹ́ wí pé, Dáfídì kọ lu odi alágbára ti Ṣíónì, ìlú ńlá Dáfídì Dáfídì ti wí pé Ẹnikẹ́ni tí ó bá darí àti kọlu àwọn ará Jébúsì ni yóò di olórí balógun, Jóábù ọmọ Sérúíà lọ sókè lákòókọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó sì gba olórí Dáfídì sì mú lọ sókè ibùgbé nínú odi alágbára, bẹ́ẹ̀ ní a sì ń pè é ni ìlú Dáfídì Ó sì kọ́ àwọn ìlú náà yíkákiri Rẹ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn alátìlẹ́yìn ibi ìtẹ́jú ilẹ̀ si àyíká ògiri Nígbà tí Jóábù sì pa ìyókù àwọn ìlú náà run Nígbà náà Dáfídì sì jẹ́ alágbára kún alágbára nítorí pé Olúwa àwọn ọmọ ogun wà pẹ̀lú Rẹ̀ Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè alágbára ọkùnrin Dáfídì, àwọn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì fún ìjọba Rẹ̀ ní àtìlẹ́yìn tó lágbára láti mú un tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sèlérí èyí sì ni iye àwọn alágbára ọkùnrin Dáfídì Jásóbéámù ọmọ Hákúmónì, òun sì ni olórí nínú àwọn ìjòyè, ó sì gbé ọ̀kọ̀ Rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa ní ogun ẹ̀ẹ̀kan Lẹ́yìn Rẹ̀ sì ni Élíásárì ọmọ Dódáì àwọn ará Áhóhì, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta ọkùnrin alágbára Ó sì wà pẹ̀lú Dáfídì ní Pásídámímù nígbà tí àwọn ará Fílístínì kó ara wọn jọ láti jagun, níbi tí ilẹ̀ kan wà tí ó kún fún ọkà báálì Àwọn ènìyàn sì sálọ kúrò níwájú Fílístínì Ṣùgbọ́n wọ́n mú ìdúró wọn ní àárin pápá náà Wọ́n sì gbà a wọ́n sì gún àwọn ará Fílístínì mọ́lẹ̀, Olúwa sì mú ìgbàlà ńlá fún wọn Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dáfídì wá lọ sí orí àpáta nínú ìhò Ádúlámù Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Fílístínì sì dúró ní àfonífojì ní orí òkè Réfáímù Ní àsìkò náà Dáfídì sì wà nínú ibi gíga àti àwọn ará Fílístínì modi sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Dáfídì sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, Áà, ẹnìkan yóò ha buomi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù fún un mu Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Fílístínì, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ó sì gbé padà tọ Dáfídì wá Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú dípò, ó sì tú jáde níwájú Olúwa Kí Ọlọ́run dẹ́kun kí èmi ó má ṣe se èyí! ó wí pé Se kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹnití ó fi ẹ̀mí Rẹ̀ wéwu Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dáfídì kò ní mu ú Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá Ábíṣáì arákùnrin Jóábù ìjòyè àwọn mẹ́ta Ó sì gbé ọ̀kọ̀ Rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀dúnrún àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta Ó sì gba ìlọ́po ọlá lórí àwọn mẹ́tẹ̀ta ó sì di olórí wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka kún ara wọn Bẹ́náyà ọmọ Jéhóíádà ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kábísélì, ẹni tí ó se iṣẹ́ agbára ńlá Ó sì pa méjì nínú àwọn ọkùnrin tí ó dára jù, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákókò sno ó sì pa kìnnìún kan Ó sì pa ara Éjíbítì ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Éjíbítì wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdubú igi àwunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ Rẹ̀, Bénáyà sọ̀kalẹ̀ lórí Rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀ Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Éjíbítì ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ Rẹ̀ Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin Bénáìá ọmọ Jéhóíádà ohun náà pẹ̀lú sì di ọlálá gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n lọ, ṣùgbọ́n a kò káà láàrin àwọn mẹ́tẹ̀ta Dáfídì sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀sọ́ Àwọn akọni ọkùnrin náà nìyí Ásáhélì arákùnrin Jóábù, Élíhánánì ọmọ Dódò láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Ṣámótù ará Hárórì, Hélésì ará Pélónì Írà ọmọ Íkéṣì láti Tékóà, Ábíésérì láti Ánátótì, Ṣíbékíà ará Húṣátì, láti ará Áhóhì Máháráì ará Nétófà, Hélédì ọmọ Báánà ará Nétófà, Ítaì ọmọ Ríbáì láti Gíbéà ní Bẹ́ńjámínì, Bẹ́náyà ará Pírátónì, Húráì láti odò Gáṣì, Ábíélì ará Áríbátì, Ásímáfétì ará Báhárúmù Élíábà ará Ṣáíbónì Àwọn ọmọ Háṣémù ará Gísónì Jónátanì ọmọ ṣágè ará Hárárì Áhíámù ọmọ sákárì ará Hárárì, Élífálì ọmọ Úrì Héférì ará Mékérátì, Áhíjà ará Pélónì, Hésírónì ará Kárímélì Náráì ọmọ Ésíbáì, Jóẹ́lì arákùnrin Nátanì Míbárì ọmọ Hágárì, Ṣélékì ará Ámónì, Náháráì ará Bérótì ẹni tí ó jẹ́ áru ìhámọ́ra Jóábù ọmọ Ṣérúyà Írà ará Ítírì, Gárébù ará Ítírì, Húríyà ará Hítì Ṣábádì ọmọ Áháláyì Ádínà ọmọ Ṣísà ará Réúbẹ́nì, ẹni tí ó jẹ́ ìjòyè ará Réubẹ́nì, àti pẹ̀lú ọgbọ́n Rẹ̀ Hánánì ọmọ Mákà Jóṣáfátì ará Mítínì Úsíà ará Ásílérátì, Ṣámà àti Jégiẹ́lì àwọn ọmọ Hótanì ará Áróérì, Jédíáélì ọmọ Ṣímírì, àti arákùnrin Jóhà ará Tísì Élíélì ará Máháfì Jéríbáì àti Jóṣáfíà àwọn ọmọ Élánámì, Ítímáì ará Móábù, Élíélì, Óbédì àti Jásídì ará Mésóbà Àwọn Ọ̀gágun Tí Ó Dúró Ti Dáfídì Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ní Ṣíkílágì Nígbà tí ó sá kúrò níwájú Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kísì Áhíésérì Olórí wọn àti Jóáṣì àwọn ọmọ Ṣémà ará Gíbéà Jésíélì àti pélétì ọmọ Ásímáfétì, Bérákà, Jéhù ará Ánátótì Àti Íṣímáyà ará Gíbíónì, ọkùnrin alágbára kan lára àwọn ọgbọ̀n ẹni tí ó jẹ́ olórí nínú àwọn ọgbọ̀n Jeremáyà, Jáhásíélì, Jóhánánì, Jósábádì ará Gédérà, Élúsáì, Jérímótì, Béálíà, Ṣémáríà àti Ṣéfátíyà ará Hárófì Élíkánà, Íṣái, Ásárélì, Jóésérì àti Jáṣóbéà ará kórà Àti Jóélà, àti Ṣébádíà àwọn ọmọ Jéróhámù láti Gédárì Díẹ̀ lára àwọn ará Gádì yà sọ́dọ̀ Dáfídì ní ibi gíga ní ihà Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di àṣà àti ẹsin mú Ojú wọn sì dàbí ojú kìnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè Ésérì sì jẹ́ ìjòyè, Ọbádáyà sì jẹ́ igbékejì akọgun, Élíábù ẹlẹ́kẹ́ta, Míṣimánà ẹlẹ́kẹ́rin, Jeremíà ẹlẹ́ẹ̀kárùn-ún Átaì ẹlẹ́kẹ́fà, Ẹlíélì èkéje, Jóhánánì ẹlẹ́kẹ́jọ Élísábádì ẹlẹ́ẹ̀kẹ́sàn-án Jeremíàh ẹlẹ́kẹ́wàá àti Mákíbánáì ẹlẹ́kọ́kànlá Àwọn ará Gádì wọ́n sì jẹ́ olórí ogun ẹni tí ó kéré jù sì jẹ́ àpapọ̀ ọgọ́rùn-ún, àti fún ẹni tí ó pọ̀jù fún ẹgbẹ̀rún Àwọn ni ẹni tí ó rékọjá Jọ́dánì ní oṣù àkọ́kọ́ nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè Rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó ń gbé nínú àfonífojì, lọ sí ìlà oòrùn àti níhà ìwọ̀ oòrùn Ìyòókù ará Bẹ́ńjámínì àti àwọn díẹ̀ ọkùnrin láti Júdà lọ sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ní ibi gíga Dáfídì sì lọ láti lọ pàdé wọn ó sì wí fún wọn pé, Tí ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi lálàáfíà, láti ràn mí lọ́wọ́ mo sẹtan láti mú un yín wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ṣùgbọ́n tí ẹ bá wá láti dá mi sí fún àwọn ọ̀ta mi nígbà tí ọwọ́ mi bá mọ́ kúrò nínú ìwà agbára, kí Ọlọ́run àwọn baba wa kí ó sì ri kí ó sì ṣe ìdájọ́ Nígbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ wa sórí Ámásáyà ìjòyè àwọn ọgbọ̀n, ó sì wí pé Tìrẹ ni àwa ń se, ìwọ Dáfídì! Àwa pẹ̀lú rẹ, ìwọ ọmọ Jésè! Àlàáfíà, àlàáfíà fún o, àti àlàáfíà fún àwọn tí ó ràn ó lọ́wọ́, nítorí Ọlọ́run Rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì gbà wọ́n ó sì mú wọn jẹ olórí ẹgbẹ́ ogun Díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin Mánásè sì yà sí ọ̀dọ̀ Dáfídì nígbà tí ó lọ pẹ̀lú àwọn ará Fílístínì láti bá Ṣọ́ọ̀lù jà Nígbà tí Dáfídì lọ sí Ṣíkílágì, àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin ti Mánásè ẹnití ó sì yà sọ́dọ̀ Rẹ̀ Ádínà, Jósábádì, Jédíáélì, Míkáẹ́lì, Jósábádì, Élíhù àti Ṣílátì, àwọn olórí ìrẹ́pọ̀ ti ẹgbẹgbẹ̀rún ní Mánásè Wọ́n sì ran Dáfídì lọwọ lórí ẹgbẹ́ ogun náà, nítorí gbogbo wọn ni akọni ènìyàn àwọn sì tún ni olórí nínú àwọn ọmọogun Rẹ̀ Ọjọ́ dé ọjọ́ ni àwọn ọkùnrin wá láti ran Dáfídì lọ́wọ́, títí tí ó fi ní àwọn ológun ńlá, bí ogun Ọlọ́run, Àwọn wọ̀nyí sì ni iye ọkùnrin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun àwọn ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì láti yí ìjọba Dáfídì padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Ọkùnrin Júdà, gbé àṣà àti ọ̀kọ̀, ẹgbẹ̀ta lé lọ́gọ́rin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun Àwọn ọkùnrin Símónì, akọni tó mú fún ogun sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin Àwọn ọkùnrin Léfì ẹgbàájì ó le ẹgbẹ̀ta , Pẹ̀lú Jéhóíádà, olórí ìdílé Árónì pẹ̀lú ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ènìyàn , Àti Sádókì akọni ọ̀dọ́mọkùnrin, pẹ̀lú àwọn méjìlélógún ìjòyè láti ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé Rẹ̀ Àwọn arákùnrin Bẹ́ńjámínì ìbátan ọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù ẹgbẹ̀ẹ́dógún , ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtọ́ sí ilé Ṣọ́ọ̀lù títí di ìgbà náà àwọn arákùnrin Éfúráímù, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ẹgbàwá ó le ẹgbẹ̀rin Àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba-ẹgbàásàn Àwọn ọkùnrin Ísákárì, àwọn ẹni tí ó mọ ìgbà yẹn ó sì mọ ohun tí Ísírẹ́lì yóò se ìgbà àwọn ìjòyè, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìbátan wọn lábẹ́ òfin wọn Àwọn ọkùnrin Ṣébúlúnì, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú orísirísi ohun èlò ìjà, láti ran Dáfídì lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàámẹ́dọ́gbọ̀n Àwọn ọkùnrin Náfítalì, ẹgbẹ̀rún ìjòyè àpapọ̀ pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún Ọkùnrin tí wọ́n gbé àṣà àti ọ̀kọ̀ wọn Àwọn ọkùnrin Dánì, tí wọ́n setan fún ogun ẹgbàámẹ́talá Àwọn ọkùnrin Áṣérì, àwọn tí ó ti ní ìmọ̀ sójà múra fún ogun ọ̀kẹ́ méje Lati ìlà òrùn Jódánì, ọkùnrin Réubénì, Gádì, àti ìdájì ẹ̀yà Mánásè, dìmọ́ra pẹ̀lú gbogbo onírúurú ohun èlò ìjà ọ̀kẹ́ mẹ́fà Gbogbo èyí ni àwọn ọkùnrin ológun tí ó fi ara wọn fún ogun láti ṣe iṣẹ fún nínú ẹgbẹ́ Wọ́n wá sí Hébrónì tí ó kún fún ìpinnu láti fi Dáfídì jẹ́ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì Gbogbo àwọn ìyókù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ́n sì jẹ́ onínú kan láti fi Dáfídì jọba Àwọn ọkùnrin náà lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀ pẹ̀lú Dáfídì, wọ́n jẹ, wọ́n sì ń mu, nítorí ìdílé wọn ti pèṣè oúnjẹ fún wọn Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jínjìn gẹ́gẹ́ bí Ísákárì, Ṣébúlúnì àti Náfítanì gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí Ràkunmí, àti lórí ìbáákà àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èṣo àjàrà gbígbẹ, èṣo ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Ísírẹ́lì Gbígbé Padà Àpótí Ẹ̀rí Dáfídì sì gbérò pẹ̀lú olúkúlùkù àwọn ìjòyè Rẹ̀, àwọn aláṣẹ ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn aláṣẹ́ ọgọ́rùn ún Ó sì wí fún gbogbo àwọn ìjọ Ísírẹ́lì pé Tí ó bá dára lójú yín àti tí ó bá ṣe jẹ́ àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa, jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí ọ̀nà jínjìn àti gbígbòòrò sí àwọn arákùnrin wa tó kù ní gbogbo àwọn agbègbè ìlú Ísírẹ́lì àti pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn nínú ìlú wọn àti pápá oko tútù, láti wá kó ara wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ wa Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa padà sọ́dọ̀ wa, nítorí wí pé àwa kò ṣe ìwádìí nípa Rẹ̀ ní àsìkò ìjọba Ṣọ́ọ̀lù Gbogbo ìjọ náà sì gbà láti ṣe èyí nítorí ó dàbí wí pé ó tọ lójú gbogbo àwọn ènìyàn Nígbà náà ni Dáfídì pe gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣíhórì ní Éjíbítì lọ sí Lébò ní ọ̀nà à bá wọ Hámátì, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati Jéárímù Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú Rẹ̀ lọ sí Báláhì ti Júdà láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Olúwa tí a fi orúkọ Rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrin kérúbù-gòkè wá Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run láti ilé Ábínádábù lórí kẹ̀kẹ́ túntún, Usà àti Áhíò ń sọ́ ọ Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú ohun èlò orin olóhùn gooro, písátérù, tíńbálì, síńbálì àti ìpè Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ pakà ti Kídónì, Úsà na ọwọ́ Rẹ̀ síta láti di àpótì ẹ̀rí Olúwa mú, nítorí màlúù kọ̀ṣẹ̀ Ìbínú Olúwa , sì ru sí Úsà, ó sì lùú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ Rẹ̀ lórí Àpótí ẹ̀rí Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run Nígbà náà Dáfídì sì bínú nítorí ìbínú Olúwa ké jáde lórí Úsá, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní péresì-Ùsà Dáfídì sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì bèèrè pé, Báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Olórun sí ọ̀dọ̀ mi Kò gbé àpótí ẹ̀rí náà wá sí ọ̀dọ̀ ará Rẹ̀ ní ìlú ti Dáfídì dípò èyí, ó sì gbé e sí ẹ̀gbé, sí ilé Obedi-Édómù ará Gítì Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì wà lọ́dọ̀ àwon ará ilé Obedi-Édómù ní ilé Rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, Olúwa sì bùkún agbo ilé àti gbogbo ohun tí ó ní Ilé Àti Ìdílé Dáfídì Nísinsìn yìí Hírámù àti ọba Tírè rán oníṣẹ́ sí Dáfídì, àti pẹ̀lú igi kédérì pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀lé àti gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ààfin fún un Dáfídì sì mọ Ísírẹ̀lì àti pé Olúwa ti fi òun ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì àti pé Ìjọba Rẹ̀ ga jùlọ nítorí ti àwon ènìyàn Rẹ̀ Ní Jérúsálẹ́mù Dáfídì mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di bàbá àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀ Ṣámúyà, Ṣóbábù, Nátanì, Ṣólómónì, Íbárì, Élíṣúà, Élífélétì, Nógà, Néfégì, Jáfíà, Élísámà, Bélíádà, àti Élífélétì Nígbà tí àwọn ará Fílístínì gbọ́ pé a ti fi àmì òróró yàn Dáfídì ní ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dáfídì gbọ́ nípa Rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn Nísinsìn yìí àwọn ará Fílístínì ti wá láti gbógun ti àfonífojì Réfáímù Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run wí pé Kí èmi kí ó gòkè tọ àwọn ará Fílístínì lọ bí Ìwọ ó ha fi wọ̀n lé mi lọ́wọ́ Olúwa sì wí fún un pé, Gòkè lọ èmi ó sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti àwọn ènìyàn Rẹ̀ gòkè lọ sí Baali-Pérásímù, níbẹ̀ ó sì kọlù wọ́n Ó sí wí pé, Gẹ́gẹ́ bí omi tí ya jáde, Ọlọ́run ti ya Dáfídì lórí àwọn ọ̀ta mi pẹ̀lú ọwọ́ mi Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń pè ibẹ̀ ní Baali-Pérásímù Àwọn ará Fílístínì sì ti fi àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀ Dáfídì sì paá láṣẹ láti jó wọn nínú iná Lẹ́ẹ̀kan síi àwọn ará Fílístínì gbógun wọ́n sì fọ́nká àfonífojì, Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì tún bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dalóhùn pé, Má se gòké tàrà, ṣùgbọ́n ẹ yí wọn ká kí ẹ sì mú wọn níwájú igi Múlíbérì Tí ó bá sì ṣe, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ìró yíyan ẹsẹ̀ ní orí òkè igi Bálísámù, ẹ jáde fún ogun, nítorí èyí yóò fi hàn pé Ọlọ́run ti jáde níwájú rẹ láti kọlu àwọn ọmọ ogun Fílístínì Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún wọn, wọ́n sì kọ lu àwọn ọmọ ogun Fílístínì láti gbogbo ọ̀nà Gíbíónì lọ sí Géṣérì Bẹ́ẹ̀ ni òkìkí Dáfídì tàn ká gbogbo ilẹ̀ káàkiri, Olúwa sì mú kí gbogbo orílẹ̀ èdè bẹ̀rù Rẹ̀ Wọ́n Gbé Àpótí Ẹ̀rí Wá Sí Jérúsálẹ́mù Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti kọ́ ilé fún ara Rẹ̀ ní ìlú Dáfídì Ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ó sì pàgọ́ fún un Nígbà náà Dáfídì wí pé, Kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Léfì ni ó lè gbé Àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí Olúwa yàn wọ́n láti gbé àpóti ẹ̀rí Olúwa àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú Rẹ̀ títí láé Dáfídì kó gbogbo àwon ọmọ Ísírélì jọ ní Jérúsálẹ́mù láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibi tí ó ti pèṣè sílẹ̀ fún un Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Árónì àti àwọn ọmọ Léfì tí Dáfídì pèjọ papọ̀ Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kóhátì Úríélì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀ Igba ó lé ogún nínú àwọn ọmọ Mórárì Ásaíà olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀ Àádóje nínú àwọn ọmọ Gésóní Jóẹ́lì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀ Igba nínú àwọn ọmọ Élísáfálì Ṣémáíà olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀ Ọgọ́rin nínú àwọn ọmọ Hébírónì Élíélì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀ Méjìléláàdọ́fà nínú àwọn ọmọ Húsíélì Ámínádábù olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀ Dáfídì sì ránṣẹ́ pe Ṣádókù, Ábíátarì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Úríélì, Ásáíà Jóẹ́lì, Ṣémáíà, Élíélì àti Ámínádábù tí wọ́n jẹ́ Léfì Ó sì fí fún wọn pé, Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Léfì ẹ̀yin àti àwọn Léfì ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un Nítorí tí ẹ̀yin ọmọ Léfì kò gbe gòkè wá ní ìgbà àkọ́kọ́ ti Olúwa Ọlọ́run wa ya ìbínú Rẹ̀ lù wá Àwa kò sì ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Rẹ̀ nípa bí a ti ń ṣe é gẹ́gẹ́ bí ọ́nà tí a là sílẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, Ọlọ́run Ísírélì Nígbà náà ni àwọn Léfì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀pá ní èjìká wọn Gẹ́gẹ́ bí Mósè ti paá láṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa Dáfídì sọ fún àwọn olórí àwọn Léfì láti yan àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí akọrin láti kọ orin ayọ̀, pẹ̀lú àwọn ohun-èlò orin pisalitérì, dùùrù, àti Ṣíḿbálì Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Léfì yan Hámánì ọmọ Jóẹ́lì àti nínú àwọn arákùnrin Rẹ̀, Ásáfù ọmọ Bérékíà, àti nínú àwọn ọmọ Mérárì arákùnrin wọn, Étanì ọmọ Kúṣáíà àti pẹ̀lú wọn àwọn arákùnrin wọn tí a yàn bí olùrànlọ́wọ́ wọn Ṣekaríyà, Jásíélì Ṣémírámótì, Jéhíélì, Únì, Élíféléhù, Míkíméíà, àti àwọn asọ́bodè Obedi-Edomu àti Jélíélì Àwọn akọrin sì ni Hémánì, Ásáfù, àti Étanì ti àwọn ti kíḿbálì idẹ tí ń dún kíkan Ṣekaríyà, Ásíélì, Ṣémírámótì, Jẹ́híélì, Únínì, Élíábù, Máséíà àti Beniáyà àwọn tí ó gbọdọ̀ ta láétírì gẹ́gẹ́ bí àlámótì, Àti Mátítíyà, Élíféléhù, Míkínéyà, Obedi-Édómù, Jélíélì àti Ásásíyà ni ó ní láti ta ohun èlò olóhùn goro, láti darí gẹ́gẹ́ bí Ṣémínítì Kénáníyá orin àwọn ará Léfì ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa Rẹ̀ Bérékíà àti Ékáníyà ni kí ó wà gẹ́gẹ́ bí olùsọ́nà fún àpótí ẹ̀rí Ṣébéáníá, Jóṣáfátì, Nétanélì, Ámásáyì, Ṣekaríyà, Beniáyà àti Élíásérì ní àwọn àlùfáà, ti o ń fún ìpè níwájú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Obedi-Édómù àti Jéhíyà ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ olùsọ́nà fún àpótí ẹ̀rí Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ láti gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa láti ilé Obedi-Édómù, pẹ̀lú inú dídùn Nítori Ọlọ́run tì ràn wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Léfì énì tí ó gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa , akọ màlúù méje pẹ̀lú àgbò méje láti fi sé ìrúbọ Nísinsìn yìí Dáfídì sì wọ aṣọ ìgúnwà ọ̀gbọ̀ dáradára, gẹ́gẹ́ bí akọrin, àti Kenaníyà, ẹnití ó wà ní ìkáwó orin kíkọ àwọn akọrin Dáfídì sì wọ aṣọ ìgúnwà fun fun Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Ísírẹ́lì gbé àpótí ẹ̀rí àti májẹ̀mú Olúwa gòkè wá pẹ̀lú ariwo, pèlú àyíká ìhó ayọ̀ àti láti fọn fèrè ti ìpè, àti kíḿbálì, àti láti ta písálítérì àti dùùrù olóhun goro Bí àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa ti ń wọ ìlú ńlá Dáfídì, Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù ń wò láti ojú fèrèsé nígbà tí ó sì rí ọba Dáfídì ń jó, ó sì ń ṣe àjọyọ̀, ó sì kẹ́gàn Rẹ̀ ní ọkàn Rẹ̀ Orin Ọpẹ́ Dáfídì Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dáfídì ti pàṣẹ fún un, wọ́n sì gbé ọrẹ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run Lẹ́yìn ọrẹ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ Olúwa Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Ísírẹ́lí ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èṣo àjàrà kan Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Léfì láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa , àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa , Ọlọ́run Ísírélì Ásáfù jẹ́ olóyè Ṣémírámótì, Jéhíelì, Mátítíyà, Élíábìlì, Bénáyà, Obedi-Édómù àti Jélíélì, Àwọn ni yóò lu lẹ́rì àti dùùrù háàpù Ásáfù ni yóò lu símíbálì kíkan Àti Bénáià àti Jahaṣíélì àwọn àlùfáà ni yóò fọn ipè dédé níwájú àpótí ẹ̀rí méjẹ̀mú ti Ọlọ́run Ní ọjọ́ náà Dáfídì kọ́kọ́ fi lé Ásáfù àti àwon ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dáfídì ti ọpẹ́ sí Olúwa Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa , ẹ pe orúkọ Rẹ̀, ẹ fi iṣẹ́ Rẹ̀ hàn nínú àwọn ènìyàn fún ohun tí ó ṣe Ẹ kọrin síi, ẹ kọrin ìyìn, síi, Ẹ sọ ti gbogbo iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ Ìyìn nínú orúkọ Rẹ̀ mímọ́ jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin Olúwa kí ó yọ̀ Ẹ wá Olúwa àti agbára Rẹ̀ O wá ojú Rẹ̀ nígbà gbogbo Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe, isẹ́ ìyanu Rẹ̀ àti ídájọ́ tí Ó ti sọ A! èyin ìran ọmọ Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ Rẹ̀, àwon ọmọ Jákọ́bù, ẹ̀yin tí ó ti yàn Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa ìdájọ́ Rẹ̀ wà ní gbogbo ayé Ó ránti májẹ̀mú rẹ́ títí láé, ọ̀rọ̀ tí Ó pa láṣẹ fún ẹgbẹ̀rún ìran, Májẹ̀mu tí ó dá pẹ̀lú Ábúráhámù, ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Ísákì Ó ṣe ìdánilójú u Rẹ̀ fún Jákọ́bù gẹ́gẹ́ bí òfin, sí Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú láéláé Sí ọ, ni Èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kénánì Gẹ́gẹ́ bí àyè tí ìwọ yóò jogún Nígbà tí wọn kéré ní iye, wọ́n kéré gidigidi, wọ́n sì jẹ́ àlejò níbẹ̀, wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀ èdè sí orílẹ̀-èdè láti ìjọba kan sí èkejì Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú nítorí ti wọn, ó bá àwọn ọba wí Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi Má ṣe pa àwọn wòlíì mi lára Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé ẹ máa fi ìgbàlà Rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́ Kéde ìgbàlà à Rẹ̀ láàárin àwọn orílẹ̀-èdè, ohun ìyàlẹ́nu tí ó se láàrin gbogbo ènìyàn Nítorí títóbi ni Olúwa òun sì ni ìyìn yẹ Jùlọ òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwon Ọlọ́run lọ Nítorí gbogbo àwọn Ọlọ́run orílẹ̀ èdè jẹ́ àwọn òrìsà, ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run Dídán àti ọlá-ńlá ni ó wà ní wájú Rẹ̀ agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé Rẹ̀ Fifún Olúwa , ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ fi ògo àti ipá fún Olúwa , fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ Rẹ̀ Gbé ọrẹ kí ẹ sì wá ṣíwájú Rẹ̀ Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ Rẹ̀ Wárìrì níwájú Rẹ̀, gbogbo ayé! Ayé sì fi ìdímúlẹ̀ a kò sì le è síi Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀ Jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn Jẹ́ kí wọn kí ó sọ láàárin àwọn orílẹ̀ èdè, pé Olúwa jọba! Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, ati gbogbo ohun tí ó wà nínú Rẹ̀ Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú Rẹ̀! Nígbà náà ni igi ti ọ̀dàn yóò kọrin, Wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú Olúwa , Nítorí tí ó wá láti sèdájọ́ ayé Fi ọpẹ fún Olúwa , nítórí tí ó dára ìfẹ́ ẹ Rẹ̀ dúró títí láé Sunkún jáde, Gbà wá, Ọlọ́run Olùgbàlà a wa kówajọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀ èdè, kí àwa kí ó lè fí ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn Rẹ̀ Olùbùkún ni Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, láé àti láéláé Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé Àmín wọ́n sì Yin Olúwa Dáfídì fi Áṣáfù àti àwọn ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa láti jísẹ́ níbẹ̀ déédé, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà Ó fí Óbédì-Edomù àti méjìdín láàdọ́rin ẹlẹgbẹ́ ẹ Rẹ̀ làti siṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn Óbédí-Édómú ọmọ Jédútúnì àti Hósà pẹ̀lú jẹ́ olútọ́jú ẹnu-ọ́nà Dáfídì fi Ṣádókù àlùfáà àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀ níwájú Àgọ́ Olúwa ní ibi gíga ní Gíbíónì Láti gbé pẹpẹ ọrẹ sísun déédé, àárọ̀ àti Ìrọ̀lẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú òfin Olúwa , tí ó ti fún Ísírẹ́lì Pẹ̀lú wọn ni Hémánì àti Jédútúnì àti ìyókù tí a mú àti yàn nípaṣẹ̀ orúkọ láti fi ọpẹ́ fún Olúwa Nítorí tí ìfẹ́ Rẹ̀ dúró títí láéláé Hémánì àti Jédútúnì ni wọ́n dúró fún fifọn ìpè àti Ṣíḿibálì àti fún títa ohun èlò yòókù fún orin yíyàsọ́tọ̀ Àwọn ọmọ Jédútúnì wà ní ipò dídúró ní ẹnu-ọ̀nà Nígbà náà gbogbo àwọn ènìyàn kúrò, olúkúlùkù sí ilé láti lọ bùkún ìdílé Rẹ̀ Ìlérí Ọlọ́run Sí Dáfídì Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti fi ìdí kalẹ̀ sínú ààfin Rẹ̀, ó sọ fún Nátanì wòlíì pé, Èmi nìyí, tí ń gbé inú òpèpè ààfin kédárì nígbà tí àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa wà lábẹ́ àgọ́ Nátanì dá Dáfídì lóhùn pé, Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ Ní àsálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Nátanì wá, wí pé Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì, Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Isírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì títí di òní yìí Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Isírẹ́lì rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkankan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Ísírẹ́lì, tí èmí pàṣẹ́ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, Kí ní ṣe tí ẹ̀yín kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kédárì kọ́ fún mi   Nígbà náà, sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì pé, Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára wí Èmi mú un yín láti pápá oko tútù wá, àní kúrò lẹ́yìn agbo àgùntàn, kí ìwọ lè máa ṣe olórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì Èmi ti wà pẹ̀lú yín ní, ibi kíbi tí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ̀mi sì ti gé gbogbo àwọn ọ̀ta yín kúrò níwáju yín Nísinsin yìí Èmi yóò mú kí orúkọ rẹ kí ó dàbí orukọ àwọn ènìyàn ńlá jùlọ̀ tí ó wà ní ayé Èmi yóò sì pèṣè àyè kan fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, kí wọn kí ó lè ní ilé ti wọn kí a má sì se dàmú wọn mọ́ Àwọn ènìyàn búburú kì yóò ni wọ́n lára mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti se ní ìbẹ̀rẹ̀ Bí wọ́n sì ti ṣe láti ìgbà tí mo ti yan àwọn aṣájú lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì Èmi pẹ̀lú yóò sẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀ta yín  Èmi sọ fún yín pé Olúwa yóò kọ́ ilé kan fún yín Nígbà ti ọjọ́ rẹ bá kọjá, tí ìwọ bá lọ láti lọ bá àwọn baba à rẹ, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ sókè láti rọ́pò rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ tìrẹ, Èmi yóò sì fìdí ìjọba Rẹ̀ kalẹ̀ Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún mi, èmi yóò sí fi ìdí ìtẹ́ Rẹ̀ kalẹ̀ títí láé Èmi yóò jẹ́ bàbá Rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kurò lọ́dọ̀ Rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo se mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú Rẹ̀ Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé ìtẹ́ Rẹ̀ ni a ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé   Nátanì ròyìn fún Dáfídì gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti Ìfihàn yí Nígbà náà, ọba Dáfídì wọlé lọ, ó sì jòkó níwájú Olúwa ó sì wí pé Ta ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, àti ki ni ìdílé mi, tí ìwọ mú mi dé ibí Pẹ̀lú bí ẹni pé èyí kò tó lojú rẹ, Ọlọ́run Ìwọ ti sọ̀rọ̀ nipa ọjọ́ iwáju ilé ìránṣẹ́ rẹ Ìwọ ti wò mí bí ẹni pé èmi ni ẹni gbígbéga jù láàárin àwọn ọkùnrin Olúwa Ọlọ́run Kí ni ohun tí Dáfídì tún lè sọ nítorí ọlá tí o bù fún ìránṣẹ́ rẹ Nítorí tí ìwọ mọ ìransẹ́ rẹ, Olúwa Nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ rẹ, ìwọ ti ṣe ohun ńlá yìí àti láti fi gbogbo ìleri ńlá yìí hàn Kò sí ẹnìkan bí ì rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan àfi ìwọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí à ti gbọ́ pẹ̀lú etí ara wa Pẹ̀lú ta ni ó dà bí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì-orílẹ̀ èdè kan ní ayé, tí Ọlọ́run jáde lọ láti ra àwọn ènìyàn kan padà fún ara Rẹ̀, àti láti lè ṣe orúkọ fún ara à rẹ, àti lati ṣe ohun ńlá àti ọwọ́ ìyanu nípa lílé àwọn orílẹ̀ èdè kúrò níwáju àwọn ènìyàn Rẹ̀, ẹni tí ó gbà là láti Éjíbítì Ìwọ se àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì ní tìrẹ láéláé ìwọ Olúwa sì ti di Ọlọ́run wọn Nisinsìn yìí, Olúwa , Jẹ́ kí ìlérí tí ìwọ ti se fún ìransẹ́ rẹ àti ilé Rẹ̀ di fífi ìdí múlẹ̀ títí láé Ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti se ìlérí Kí ó lè di fifi ìdí múlẹ̀ àti kí orúkọ rẹ di gbígbéga títí láé Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin yóò wí pé, Olúwa , ni Ọlọ́run Isírẹ́lì Ilé ìransẹ́ rẹ Dáfídì sì ni a ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ níwáju rẹ Ìwọ, Ọlọ́run mi, ti fihan ìránṣẹ́ rẹ pé, ìwọ yóò kọ́ ilé fún un Bẹ́ẹ̀ ni ìransẹ́ rẹ ti ní ìgboyà láti gbàdúrà sí ọ Olúwa , ìwọ ni Ọlọ́run Ìwọ ti fi ìlérí dídára yìí fún ìránṣẹ́ rẹ Nísinsìn yìí ó ti tẹ́ ọ lọ́rùn láti bùkún ilé ìransẹ́ rẹ kí ó lè tẹ̀ṣíwájú ní ojú rẹ nitorí ìwọ, Olúwa , ti bùkún un, a ó sì bùkun-un títí láéláé Àwọn Ìṣẹ́gun Dáfídì Ní àkókò kan, Dáfídì kọlu àwọn ará Fílístínì, ó sì sẹ́gun wọn Ó sì mú Gátì àti àwọn ìlétò agbègbè Rẹ̀ kúrò lábẹ́ ìdarí àwọn ará Fílístínì Dáfídì borí àwọn ará Móábù, wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀, wọ́n sì mú owó òde wá Ṣíbẹ̀, Dáfídì bá Hádádáṣérì ọba Ṣóbà jà, jìnnà láti fi ìdarí Rẹ̀ kalẹ̀ lẹ́bàá odò Éúfúrétè Dáfídì fi agbára gba ẹgbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ Rẹ̀, ẹgbẹ̀rún méje a gun kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá méjì ológun ilẹ̀ Ó sì já gbogbo ọgọ́rùn ún iṣan ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹsin náà Nígbá ti àwọn ará Áráméà nì ti Dámásíkù wá láti ran Hadadésérì ọba Ṣóbà lọ́wọ́, Dáfídì lu ẹgbàá méjì wọn bọ lẹ̀ Ó sì fi àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ sínú ìjọba Áráméánì ti Dámásíkù, àwọn ará Áráméánì sì ń sìn ní abẹ́ Rẹ̀, wọ́n sì mú owó ìsákọ́lẹ̀ wá Olúwa sì ń fún Dáfídì ní ìṣẹ́gun ní ibi gbogbo tí ó bá lọ Dáfídì mú apata wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadésérì gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jérúsálẹ́mù Láti Tébà àti Kúnì, ìlú tí ó jẹ́ ti Hádádéṣérì, Dáfídì mú ọ̀pọ̀ tánganran tí Ṣólómónì lò láti fi ṣe òkun tan-gan-ran, àwọn òpó àti orísìí ohun èlò tan-gan-ran Nígbà tí Tóù ọba Hámátì gbọ́ pé Dáfídì ti borí gbogbo ọmọ ogun Hádádéṣérì ọba Ṣóbà Ó rán ọmọ Rẹ̀ Ádórámì sí ọba Dáfídì láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun Rẹ̀ nínú ogun lórí Hádádéṣérì, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tóù Ádórámì mú oríṣiríṣi ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti tan-gan-ran wá Ọba Dáfídì ya ohun èlò wọ̀n yí sí mímọ́ fún Olúwa , gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí Édómù àti Móábù, ará Ámónì àti àwọn ará Fílístínì àti Ámálékì Ábíṣáì ọmọ Ṣeruíà, lu méjìdínlógojì ẹgbẹ̀rin ará Édómù bolẹ̀ ní àfonífojì iyọ̀ Ó fi Gárísónì sí Édómù, gbogbo àwọn ará Édómù sì ń sìn ní abẹ́ Dáfídì Olúwa fún Dáfídì ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibí tí ó bá lọ Dáfídì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn Rẹ̀ Jóábù ọmọ Ṣérúyà jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì jẹ́ akọ̀wé ìrántí Ṣádókù ọmọ Áhítúbì àti Áhímélékì ọmọ Ábíátarì jẹ́ àwọn àlùfáà Ṣáfíṣà jẹ́ akọ̀wé Bénáyà ọmọ Jéhóíádà jẹ́ olórí àwọn kérétì àti pélétì àwọn ọmọ Dáfídì sì jẹ́ àwọn olóyè onísẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba Ogun Tí Ó Dojúkọ Àwọn Ará Ámónì Ní àkókò yí, Náháṣì ọba àwọn ará Ámónì kú, ọmọ Rẹ̀ sì rọ́pò Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Dáfídì rò wí pé Èmi yóò fi inú rere hàn sí Hánúnì ọmọ Náháṣì, nítorí baba a Rẹ̀ fi inú-rere hàn sí mi Bẹ́ẹ̀ ni, Dáfídì rán àwọn aṣojú lọ láti lọ fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn sí Hánúnì níti baba a Rẹ̀ Nígbà tí àwọn ọkùnrin Dáfídì wá sí ọ̀dọ̀ Hánúnì ní ilẹ̀ Àwọn ará Ámónì láti fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn sí i, Àwọn ọkùnrin ọlọ́lá ti Ámónì sọ fún Hánúnì pé, Ṣé ìwọ rò pé Dáfídì ń bu ọlá fún Baba rẹ nípa rírán àwọn ọkùnrin sí ọ láti fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn Ṣé àwọn ọkùnrin Rẹ̀ kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti wá kiri àti samí sita orílẹ̀ èdè àti láti bì í ṣubú Bẹ́ẹ̀ ni Hanúnì fi ipá mú àwọn ọkùnrin Dáfídì, fá irun wọn, wọ́n gé ẹ̀wù wọn kúrò ní àárin ìdí Rẹ̀, ó sì rán wọn lọ Nígbà tí ẹnìkan wá, tí ó sì sọ fún Dáfídì nípa àwọn ọkùnrin Rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ láti lọ bá wọn, nítorí wọ́n ti di rírẹ̀ sílẹ̀ gidigidi Ọba wí pe, Dúró ní Jeríkò títí tí irungbọ̀n yín yóò fi hù, Nígbà náà ẹ padà wá Nígbà tí àwọn ará Ámónì rí i wí pé wọ́n ti di ẹ̀ṣẹ̀ ní ihò imú Dáfídì, Hánúnì àti àwọn ará Ámónì rán ẹgbẹ̀rún talẹ́ntì fàdákà láti gba iṣẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn agun-kẹ̀kẹ́ láti síríà Náháráímù, Ṣíríà Mákà àti Ṣóbà Wọ́n gba iṣẹ́ ẹgbẹ̀rin méjìlélọ́gbọ̀n kẹ̀kẹ́ àti agun-kẹ̀kẹ́ àti ọba Mákà pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọmọ ogun Rẹ̀ tí ó wá pàgọ́ ní ẹ̀bá Médébà, nígbà tí àwọn ará Ámónì kó jọ pọ̀ láti ìlú wọn, tí wọ́n sì jáde lọ fún ogun Ní gbígbọ́ eléyìí, Dáfídì rán Jóábù jáde pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun ọkùnrin tí ó le jà Àwọn ará Ámónì jáde wá, wọ́n sì dá isẹ́ ogun ní àbáwọlé sí ìlú ńlá wọn, nígbà tí àwọn ọba tí ó wá, fún rara wọn wà ni orílẹ̀ èdè tí ó sí sílẹ̀ Jóábù ri wí pé àwọn ìlà ogun wà níwájú àti ẹ̀yìn òun Bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ogun tí ó dára ní Ísírẹ́lì, o sì tẹ́ ogun wọn sí àwọn ará Ṣíríà Ó fi ìyókù àwọn ọkùnrin náà sí abẹ́ àkóso Ábíṣáì arákùrin Rẹ̀, a sì tẹ́ wọn kí wọn dojúkọ àwọn ará Ámónì Jóábù wí pé Tí àwọn ará Ṣíríà bá le jù fún mi, nígbà náà, ìwọ ni kí o gbà mí Ṣùgbọ́n tí àwọn ará Ámónì bá le jù fún ọ, Nígbà náà èmi yóò gbà ọ́ Jẹ́ alágbára kí ẹ sì jẹ́ kí a jà pẹ̀lú ìgboyà fún àwọn ènìyàn wa àti àwọn ìlú ńlá ti Ọlọ́run wa Olúwa yóò ṣe ohun tí ó dára ní ojú Rẹ̀ Nígbà náà Jóábù àti àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú Rẹ̀ lọṣíwájú láti lọ jà pẹ̀lú àwọn ará Ṣíríà Wọ́n sì sálọ kúrò níwájú Rẹ̀ Nígbà ti àwọn ará Ámónì ri pé àwọn ará Ṣíríà ń sálọ, àwọn náà sálọ kúrò níwájú arákùnrin Rẹ̀ Ábíṣáì Wọ́n sì wọ inú ìlú ńlá lọ Bẹ́ẹ̀ ni Jóábù padà lọ sí Jérúsálẹ́mù Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ará Ṣíríà rí wí pé àwọn Ísírẹ́lì ti lé wọn, wọ́n rán ìránṣẹ́ A sì mú àwọn ará Ṣíríà rékọjá odò wá, pẹ̀lú Ṣófákì alákóso ọmọ ogun Hádádésérì, tí ó ń darí wọn Nígbà tí a sọ fún Dáfídì nípa èyí, ó pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ wọ́n sì rékọjá Jódánì Ó lọ ṣíwájú wọn, ó sì fa ìlà ogun dojúkọ wọ́n Dáfídì fa ìlà Rẹ̀ láti bá àwọn ará Ṣíríà jagun wọ́n sì doju ìjà kọ ọ́ Ṣùgbọ́n wọ́n sálọ kúrò níwájú Ísírẹ́lì, Dáfídì sì pa ẹgbẹ̀rún méje agun-kẹ̀kẹ́ wọn àti ẹgbàá mẹ́rin ọmọ-ogun ẹlẹ́sẹ̀ Ó pa Ṣófákì alákóṣo ọmọ ogun wọn pẹ̀lú Nígbà tí àwọn ẹrú Hádádé-ṣérì ríi wí pé Ísírẹ́lì ti borí wọn, wọ́n ṣe àlàáfíà pẹ̀lú Dáfídì, wọ́n sì ń sìn ní abẹ́ ẹ Rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ará Ṣíríà kò ní ìfẹ́ sí ríran àwọn ará Ámónì lọ́wọ́ mọ́ Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Réúbẹ́nì, Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì, Ṣébúlúnì, Dánì, Jóṣẹ́fù, Bẹ́ńjámínì Náfítanì, Gádì àti Áṣérì Àwọn ọmọ Júdà Érì, Ónánì àti Ṣélà, àwọn mẹ́tẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kénánì, ọmọbìnrin Súà Érì àkọ́bí Júdà, ó sì burú ní ojú Olúwa Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á Támárì, aya ọmọbìnrin Júdà, ó sì bí Fárésì àti Ṣérà sì ní ọmọ márùn ún ní àpapọ̀ Àwọn ọmọ Fárésì Hésírónì àti Hámúlù Àwọn ọmọ Ṣérà Ṣímírì, Étanì, Hémánì, Kálíkólì àti Darà, gbogbo wọn jẹ́ márùn ún Àwọn ọmọ Kárímì Ákárì, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Ísírẹ́lì nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀ Àwọn ọmọ Étanì Áṣáríyà Àwọn ọmọ tí a bí fún Hésírónì ni Jéráhímélì, Rámù àti Kélẹ́bù Rámù sì ni baba Ámínádábù, àti Ámínádábù baba Náṣónì olórí àwọn ènìyàn Júdà Náṣónì sì ni baba Sálímà, Sálímà ni baba Bóásì, Bóásì baba Óbédì àti Óbédì baba Jésè Jésè sì ni Baba Élíábù àkọ́bí Rẹ̀ ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kẹjì sì ni Ábínádábù, ẹlẹ́ẹ̀kẹta ni Ṣíméà, Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin Nàtaníẹ́lì, ẹlẹ́ẹ̀káàrùn-ún Rádáì, ẹlẹ́ẹ̀kẹfà Ósémù àti ẹlẹ́ẹ̀keje Dáfídì Àwọn arábìnrin wọn ni Ṣérúà àti Ábígáílì Àwọn ọmọ mẹ́ta Ṣérúà ni Ábíṣáì, Jóábù àti Ásáélì Ábígáílì ni ìyá Ámásà, ẹni tí baba Rẹ̀ sì jẹ́ Jétérì ará Íṣímáẹ́lì Kélẹ́bù ọmọ Hésírónì ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó Rẹ̀ Ásúbà Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Rẹ̀ Jéṣérì, Ṣóbábù àti Árídónì Nígbà tí Ásúbà sì kú, Kélẹ́bù sì fẹ́ Éfúrátì ní aya, ẹni tí ó bí Húrì fún un Húrì ni baba Úrù, Úrù sì jẹ́ baba Bésálélì Nígbà tí ó yá, Hésírónì sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Mákírì baba Gílíádì ó sì bí Ṣégúbù Ṣégúbù sì jẹ́ bàbá Jáírì, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́talélógún ní ilẹ̀ Gílíádì Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Mákírì Baba Gílíádì Lẹ́yìn tí Hésírónì sì kú ni Kélẹ́bù Éfúrátà, Ábíà ìyàwó Rẹ̀ ti Hésírónì sì bí Áṣúrì baba Tẹ́kóà fún un Ọmọ Jéráhímélì àkọ́bí Hésírónì Rámà ọmọ àkọ́bí Rẹ̀ Búnà, Órénì, óṣémù àti Áhíjà Jéráhímélì ní ìyàwó mìíràn, ẹni tí orúkọ Rẹ̀ ń jẹ́ Átarà ó sì jẹ́ ìyá fún Ónámù Àwọn ọmọ Rámà àkọ́bí Jéráhímélì Másì, Jámínì àti Ékérì Àwọn ọmọ Ónámù Ṣámáì àti Jádà Àwọn ọmọ Ṣámáì Nádábù àti Ábísúrì Orúkọ ìyàwó Ábísúrì ni Ábíháílì ẹni tí ó bí Áhíbánì àti Mólídì Àwọn ọmọ Nádábù Ṣélédì àti Ápáímù Ṣélédì sì kú láìsí ọmọ Àwọn ọmọ Ápáímù Isì, ẹnití ó jẹ́ baba fún Ṣésánì Ṣésánì sì jẹ́ baba fún Áhíláì Àwọn ọmọ Jádà, arákùnrin Ṣámáì Jétérì àti Jónátanì Jétérì sì kú láìní ọmọ Àwọn ọmọ Jónátanì Pélétì àti Ṣásà Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jéráhímẹ́lì Ṣésánì kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Éjíbítì tí orúkọ Rẹ̀ ń jẹ́ Járíhà Ṣẹ́sánì sì fi ọmọ obìnrin Rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ Rẹ̀ Járíhà, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ Rẹ̀ jẹ́ Átaì Átaì sì jẹ́ baba fún Nátanì, Nátanì sì jẹ́ baba fún Ṣábádì, Ṣábádì ni baba Éfúlálì, Éfúlálì jẹ́ baba Óbédì, Óbédì sì ni baba Jéhù, Jéhù ni baba Ásáríyà, Ásáríyà sì ni baba Hélésì, Hélésì ni baba Éléáṣáì, Éléáṣáì ni baba Ṣísámálì, Ṣísámálì ni baba Ṣálúmù, Ṣálúmù sì ni baba Élísámà Àwọn ọmọ Kálébù arákùnrin Jérámélì Méṣà àkọ́bí Rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Ṣífì àti àwọn ọmọ Rẹ̀ Méréṣà, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hébúrónì Àwọn ọmọ Hébúrónì Kórà, Tápúà, Rékémù, àti Ṣémà Ṣémà ni baba Ráhámú Ráhámù sì jẹ́ baba fún Jóríkéámù Rékémù sì ni baba Ṣémáì Àwọn ọmọ Ṣémáì ni Máónì, Máónì sì ni baba Bétí-Ṣúri Éfà Obìnrin Kélẹ́bù sì ni ìyá Hárà nì, Mósà àti Gásésì, Háránì sì ni baba Gásésì Àwọn ọmọ Jádáì Régémù, Jótamù, Gésánì, Pétélì, Éfà àti Ṣáfù Mákà obìnrin Kélẹ́bù sì ni ìyá Ṣébérì àti Tíránà Ó sì bí Ṣáfà baba Mákíbénà, Ṣéfà baba Mákíbénà àti baba Gíbéà ọmọbìnrin Kélẹ́bù sì ni Ákíṣà Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kélẹ́bù Àwọn ọmọ Húrì, àkọ́bí Éfúrátà Ṣóbálì baba Kiriati-Jéárímù Ṣálímà baba Bétíléhẹ́mù àti Háréfù baba Bẹti-Gádérì Àwọn ọmọ Ṣóbálì baba Kíríátì-Jéárímù ni Háróè, ìdajì àwọn ará Mánáhítì Àti ìdílé Kíríátì-Jéárímù àti àwọn ara Ítírì, àti àwọn ará Pútì, àti àwọn ará Ṣúmátì àti àwọn ará Mísíhí-ráì láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sórátì àti àwọn ará Ésítaólì ti wá Àwọn ọmọ Ṣálímà Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àti àwọn ará Nétófátì, Atírótì Bẹti-Jóábù, ìdajì àwọn ará Mánátì, àti Ṣórì, Àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jábésì àti àwọn ọmọ Tírátì àti àwọn ará Ṣíméátì àti àwọn ará Ṣúkátì Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Kénì, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hámátì, baba ilé Kélẹ́bù Fífi Agbára Mú Rábà Ní àkókò àkọ́rọ̀ òjò, ni ìgbà tí àwọn ọba lọ sí ogun, Jóábù ṣamọ̀nà àwọn ọ̀wọ́ ọmọ ogun Ó fi ilẹ̀ àwọn ará Ámónì ṣòfò Ó lọ sí ọ̀dọ̀ Rábà Ó sì fi ogun dúró tì í Ṣùgbọ́n Dáfídì dúró sí Jérúsálẹ́mù Jóábù kọlu Rábà, ó sì fi sílẹ̀ ní ìparun Dáfídì mú adé kúrò lórí àwọn ọba wọn ìwọ̀n Rẹ̀ dàbí i talẹ́ńtì wúrà, a sì tò ó jọ pẹ̀lú àwọn òkúta iyebíye A sì gbé e ka orí Dáfídì Ó kó ọ̀pọ̀ ìkógun láti ìlú ńlá náà Ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ jáde, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ láti ṣíṣẹ́ pẹ̀lú ayùn àti ìtulẹ̀ onírin àti àáké Dáfídì ṣe eléyìí sí gbogbo àwọn ará ìlú Ámónì Nígbà náà, Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ ogun Rẹ̀ padà sí Jérúsálẹ́mù Ní ẹ̀yìn èyí ni ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Géṣérì pẹ̀lu àwọn ará Fílístínì, ní àkókò yìí ni Ṣíbékíà ará Húsà pa Ṣípáì, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Réfáì, àti àwọn ará Fílístínì ni a sẹ́gun Nínú ogun mìíràn pẹ̀lú àwọn ará Fílístínì, Élíhánánì ọmọ Jáírè pa Láhímì arákùnrin Gòláyátì ará àti, Gátì ẹni ti ó ní ọ̀kọ̀ kan tí ó dàbí ọ̀pá ahunsọ Síbẹ̀síbẹ̀ ninú ogun mìíràn, tí ó wáyé ní Gátì, ọkùnrin títóbi kan wà tí ó ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ Rẹ̀ pẹ̀lú ìka mẹ́fà ní ẹṣẹ̀ Rẹ̀ Mẹ́rìnlélógún lápapọ̀ Òun pẹ̀lú wá láti Ráfà Nígbà tí ó fí Íṣírẹ́lì sẹ̀sín Jónátanì ọmọ Ṣíméà, àrákùnrin Dáfídì, sì pa á Wọ̀nyí ni ìran ọmọ Ráfà ní Gátì, wọ́n sì subú sí ọwọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin Rẹ̀ Sátanì sì ru ọkàn Dáfídì sókè láti ka iye Ísírẹ́lì Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì wí fún Jóábù àti àwọn olórí ti àwọn ọ̀wọ́ ọmọ ogun, Lọ kí o lọ ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti Béríṣébà títí dé Dánì Kí o sì padà wá sọ fún mi kí èmi kí ó le mọ iye tí wọ́n jẹ́ Ṣùgbọ́n Jóábù dá a lóhùn pé Kí Olúwa pọ̀ sí ní ìgbà ọgọ́rùn ún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ Olúwa ọba mi, sé gbogbo wọn kì í ṣe ìránṣẹ́ Olúwa ni Kí ni ó dé tí Olúwa mi ṣe fẹ́ ṣèyí Kí ni ó de tí yóò fi mú Ísírẹ́lì jẹ̀bi Ọ̀rọ̀ ọba, bí ó ti wù kí ó rí, borí tí Jóábù Bẹ́ẹ̀ ni Jóábù kúrò ó sì jáde lọ sí Jérúsálẹ́mù Jóábù sì sọ iye tí àwọn ajagun ọkùnrin náà jẹ́ fún Dáfídì Ní gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì jásí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn tí ó lè mú idà àti pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́talélógún lé ẹgbàrún ní Júdà Ṣùgbọ́n Jóábù kó àwọn Léfì àti Bẹ́ńjámínì mọ́ iye wọn, nítorí àsẹ ọba jẹ́ ìríra fún un Àṣẹ yìí pẹ̀lú sì jẹ́ búburú lójú Olúwa , bẹ́ẹ̀ ni ó sì díyàjẹ Ísírẹ́lì Nígbà náà Dáfídì sọ fún Ọlọ́run pé, Èmi ti dẹ́ṣẹ̀ gidìgidì nípa ṣíṣe èyí Nísinsin yìí, èmi bẹ̀ ọ́, mú ìjẹ̀bi àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò Èmi ti hùwà òmùgọ̀ gidigidi Olúwa sì fi fún Gádì, aríran Dáfídì pé Lọ kí o lọ sọ fún Dáfídì pé, Èyí ní ohun tí Olúwa sọ Èmi sì fún ọ ní àwọn àṣàyàn mẹ́ta Yan ọ̀kan ninú wọn fún mi láti gbé jáde nípa rẹ   Bẹ́ẹ̀ ni Gádì lọ sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ó sì wí fún pé, Nǹkan yí ni ohun tí Olúwa sọ Yan aṣàyàn tìrẹ Ọdún mẹ́ta ìyàn, oṣù mẹ́ta gbígbá lọ niwájú àwọn ọ̀tá rẹ, pẹ̀lú idà wọn láti lé ọ bá, tàbí ọjọ́ mẹ́fà idà Olúwa ọjọ́ àjàkálẹ̀-àrùn ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn ángẹ́lì Olúwa láti pa gbogbo agbègbè Ísírẹ́lì run Nísinsi yìí ǹjẹ́, ronú bí èmi yóò ti ṣe dá ẹni tí ó rán mi lóhùn Dáfídì sì wí fún Gádì pé èmi wà nínú ìyọnu ńlá Jẹ́ kí èmi kí ó ṣubú sí ọwọ́ Olúwa , nítorí tí àánú Rẹ̀ pọ̀ gidigidi Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí èmi kí o ṣubú sí ọwọ́ àwọn ènìyàn Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa rán àjàkálẹ̀-àrùn lórí Ísírẹ́lì, ẹgbàá márùndínlógójì ènìyàn Ísírẹ́lì sì kú Ọlọ́run sì rán ańgẹ́lì láti pa Jérúsálẹ́mù run Ṣùgbọ́n bí áńgẹ́lì ti ń ṣe èyí, Olúwa sì ríi Ó sì káàánú nítorí ibi báà, ó sì wí fún áńgẹ́lì tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró Ańgẹ́lì Olúwa náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Áráúnà ará Jébúsì Dáfídì sì wòkè ó sì rí áńgẹ́lì Olúwa dúró láàrin ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ Rẹ̀ tí ó sì nàá sórí Jérúsálẹ́mù Nígbà náà Dáfídì àti àwọn àgbààgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀ Dáfídì sì wí fún Ọlọ́run pé, Èmi ha kọ́ ni mo paláṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò dára, wọ̀nyí ni àgùntàn Kí ni wọ́n ṣe Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdíle mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-àrùn yìí kí ó dúró lóri àwọn ènìyàn rẹ Nígbà náà ańgẹ́lì Olúwa náà pàṣẹ̀ fún Gádì láti sọ fún Dáfídì láti lọ sókè kí ó sì kọ́ pẹpẹ fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà ti Órínánì ará Jébúsì Bẹ́ẹ̀ni Dáfídì sì gòkè lọ pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí Gádì ti sọ ní orúkọ Olúwa Nígbà tí Órínánì sì ń pakà lọ́wọ́, ó sì yípadà ó sì rí áńgẹ́lì àwọn ọmọ Rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà pẹ̀lú Rẹ̀ pa ará wọn mọ́ Nígbà náà Dáfídì sì súnmọ́, Nígbà tí Órínánì sì wò tí ó sì rí, ó sì kúrò ní ilẹ̀ ìpakà ó sì doju bolẹ̀ níwájú Dáfídì pẹ̀lú ojú Rẹ̀ ní ilẹ̀ Dáfídì sì wí fún un pé, Jẹ́ kí èmi kí ó ni ibi ìpakà rẹ kí èmi kí ó sì lè kọ́ pẹpẹ fún Olúwa , kí àjàkálẹ̀-àrùn lórí àwọn ènìyàn lè dúró Tàá fún mi ní iye owó kíkún Órínánì ni ó sọ fún Dáfídì pé, Gbà á! Jẹ́ kí Olúwa ọba mi kí ó ṣe ohun tí ó dára lójú Rẹ̀ Woó, èmí yóò fún ọ ní àwọn màlúù fún ẹbọ ọrẹ ṣiṣun, àti ohun èlò ìpakà fún igi, àti ọkà fún ọrẹ oúnjẹ Èmi yóò fun ọ ní gbogbo èyí Ṣùgbọ́n ọba Dáfídì dá Órínánì lóhùn pé, Rárá, mo wà lórí àti san iye owó rẹ ní pípé, èmi kò sì ní mú fún Olúwa èyí tí ó jẹ́ tìrẹ, tàbí láti rú ẹbọ ọrẹ sísun tí kò ná mi ní ohun kan Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì san ẹgbẹ̀ta ṣékélì wúrà fún Órínánì nípa ìwọ̀n fún ibẹ̀ náà Dáfídì sì tẹ́ pẹpẹ fún Olúwa níbẹ̀ ó sì ní ẹbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ ọrẹ àlàáfíà Ó sì pe orúkọ Olúwa , Olúwa sì da lóhùn pẹ̀lú iná láti òkè ọ̀run lórí pẹpẹ fún ẹbọ ọrẹ ṣíṣun Nígbà náà Olúwa sọ̀rọ̀ sí ańgẹ́lì, ó sì gbé idà padà bọ̀ sínú àkọ̀ Rẹ̀ Ní àkókò náà nígbà tí Dáfídì sì rí wí pé Olúwa ti dá a lóhùn lórí ilẹ̀ ìpakà ti Órínán ará Jébúsì, ó sì rú ẹbọ ọrẹ sísun níbẹ̀ Àgọ́ Olúwa tí Mósè ti ṣe ní ihà, àti pẹpẹ ẹbọ ọrẹ ṣíṣun wà lórí ibi gíga ní Gíbíónì ní àkókò náà Ṣùgbọ́n Dáfídì kò lè lọ ṣíwájú Rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí tí ó bẹ̀rù nípa idà ọwọ́ ańgẹ́lì Olúwa Ìmúrasílẹ̀ Fún Ilé Tí A Kọ́ Fún Ìsìn Ọlọ́run Nígbà náà Dáfídì wí pé, Ilé Olúwa Ọlọ́run ni ó gbọdọ̀ wà níbí, àti pẹ̀lú pẹpẹ ọrẹ síṣun fún Ísírẹ́lì Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì paláṣẹ láti kó àwọn àlejò tí ń gbé ní Ísírẹ́lì jọ, àti wí pé lára wọn ni ó ti yan àwọn agbé-òkúta láti gbé òkúta dáradára láti fi kọ́lé Ọlọ́run Ó sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣọ́ fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà àti fún idẹ àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n Ó sì tún pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi Kédárì tí ó jẹ́ àìníye, nítorí pé àwọn ará Ṣídónì àti àwọn ará Tírè mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kédárì wá fún Dáfídì Dáfídì wí pé, Ọmọ mi Sólómónì ọ̀dọ́mọdé ni ó sì jẹ́ aláìní ìríri, ilé tí a ó kọ́ fún Olúwa gbọdọ̀ jẹ́ títóbi jọjọ, kí ó sì ní òkìkí àti ògo jákèjádò gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè Nítorí náà ni èmi yóò ṣe pèsè sílẹ̀ fún un Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì ṣe ìpèsè sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ó tó di wí pé ó kú Nígbà náà ó pe Sólómónì ọmọ Rẹ̀ ó sì sọ fun pé kí ó kọ́ ilé fún-un Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì Dáfídì sì wí fún Sólómónì pé, Ọmọ mi, mo sì ní-in ní ọkàn mi láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńlá ńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún-un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀ta Rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká Orúkọ Rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Sólómónì, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ fún Ísírẹ́lì lásìkò ìjọba Rẹ̀ Òun ni ẹni náà tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi Yóò sì jẹ́ ọmọ mi, èmi yóò sì jẹ́ baba Rẹ̀ èmi yóò sì fi ìdi ìtẹ́ ìjọba Rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì láéláé Nísinsìn yìí, ọmọ mi, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ Kí Olúwa kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ se aláṣẹ lórí Ísírẹ́lì, Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin Olúwa Ọlọ́run mọ́ Nígbà náà ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí tí ìwọ bá ṣe àkíyèsí láti mú àṣẹ àti ìdájọ́ àti òfin ti Olúwa ti fi fún Mósè fun Ísírẹ́lì ṣe Bẹ́ẹ̀ ni ki ìwọ jẹ́ alágbára àti onígboyà Má ṣè bẹ̀rù tàbí kí àyà má sì ṣe fò ọ́ Èmi ti gba Ìpọ́nju ńlá láti ṣe fún ile Olúwa ọ̀kẹ́ márùn ún talẹ́ńtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún talẹ́ntì fàdákà, Ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta Ìwọ sì tún le fi kún wọn Ìwọ sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣẹ́ ènìyàn àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn oníṣọ̀nà òkúta àti àwọn agbẹ́-òkúta, àti gẹ́gẹ́ bí onírúurú ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ Nínú wúrà, fàdákà àti idẹ àti irin onísọ̀nà tí kò ní ìwọ̀n Nísinsin yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ Nígbà náà Dáfídì pa á láṣẹ fún gbogbo àwọn àgbààgbà ní Ísírẹ́lì láti ran Sólónmónì ọmọ Rẹ̀ lọ́wọ́ Ó sì wí pé, Ṣé kò sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú rẹ Òun kò ha ti fi ìsinmi fún ọ lórí gbogbo ilẹ̀ Nítorí ó sì ti fi àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́ ó sì ti fi ìsẹ́gun fún ilẹ̀ náà níwájú Olúwa àti níwájú àwọn ènìyàn Nísinsìn yìí ẹ sí ọkàn yin payá àti àyà yín sí àti wá Olúwa Ọlọ́run yín Bẹ́ẹ̀ sì ni kọ́ ibi mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó le gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa àti ohun èlò mímọ́ tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, sínú ilé Olúwa tí a o kọ́ fún orúkọ Olúwa Àwọn Ará Léfì Nígbà tí Dáfídì sì dàgbà tí ó sì kún fún ọjọ́, ó sì fi Sólómónì ọmọ Rẹ̀ jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì Ó sì kó gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì Àwọn ọmọ Lefì lati ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún Dáfídì sì wí pe, Níti èyí, ẹgbàáméjìlá ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbàáta ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́ Ẹgbàájì ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà àti ẹgbàajì ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti se èyí fún ìdí pàtàkì yìí Dáfídì sì pín àwọn ọmọ Léfì sí ẹgbẹgbẹ́ láàrin àwọn ọmọ Léfì Gérísónì, Kóhátì àti Mérárì Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gérísónì Ládánì àti Ṣíméhì Àwọn ọmọ Ládánì Jéhíélì ẹni àkọ́kọ́, Ṣétanì àti Jóẹ́lì ẹ̀kẹ́ta ní gbogbo wọn Àwọn ọmọ Ṣímè Ṣélómótì, Hásíélì àti Háránì mẹ́ta ní gbogbo wọn Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Ládánì Àti ọmọ Ṣímélì Jáhátì, Ṣísà, Jéúsì àti Béríà Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣíméhì mẹ́rin ni gbogbo wọn Jáhátì sì ni alákọ́kọ́ Ṣísà sì ni ẹlẹ́kejì, ṣùgbọ́n Jéúsì àti Béríà kò ní àwọn ọmọ púpọ̀ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan Àwọn ọmọ kóhátì Ámírámù, Ísárì, Hébúrónì àti Usíélì mẹ́rin ni gbogbo wọn Àwọn ọmọ Ámírámù Árónì àti Móṣè A sì ya Árónì sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ Rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rúbọ sísun níwájú Olúwa , láti máa ṣe òjísẹ́ níwájú Rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ Rẹ̀ títí láéláé Àwọn ọmọ Mósè ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apákan ẹ̀yà Léfì Àwọn ọmọ Mósè Gérísónì àti Élíásérì Àwọn ọmọ Gérísónì Ṣúbáélì sì ni alákọ́kọ́ Àwọn ọmọ Élíásérì Réhábíà sì ni ẹni àkọ́kọ́ Élíásérì kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Réhábíà wọ́n sì pọ̀ níye Àwọn ọmọ Ísárì Ṣélómítì sì ni ẹni àkọ́kọ́ Àwọn ọmọ Hérónì Jéríyà sì ni ẹni àkọ́kọ́, Ámáríyà sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì, Jáhásíélì sì ni ẹ̀ẹ̀kẹta àti Jékáméámù ẹ̀ẹ̀kẹrin Àwọn ọmọ Húsíélì Míkà ni àkọ́kọ́ àti Íṣíà ẹ̀ẹ̀kejì Àwọn ọmọ Mérárì Máhílì àti Músì Àwọn ọmọ Máhílì Élíásárì àti Kísì Élíásérì sì kú pẹ̀lú Àìní àwọn ọmọkùnrin Ó ní ọmọbìnrin nìkan Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kísì, sì fẹ́ wọn Àwọn ọmọ Músì Málì, Édérì àti Jérímótì mẹ́ta ni gbogbo wọn Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Léfì bí ìdílé wọn Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa Nítorí pé Dáfídì ti sọ pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jérúsálẹ́mù títí láéláé Àwọn ọmọ Léfì kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn Rẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dáfídì sí, àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ Iṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ni láti ran àwọn ọmọ Árónì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tìí ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ ọrẹ, àti aláìwú pẹ̀tẹ̀, àti fún dídùn àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òṣùnwọ̀n Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àsálẹ́ Ní gbàkúgbà ẹbọ ọrẹ sísun ni wọ́n fi fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a paláṣẹ Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti paláṣẹ fún wọn Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Léfì gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún ibi mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Árónì fún ìsìn ilé Olúwa Pínpín Àwọn Àlùfáà Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Árónì Àwọn ọmọ Árónì ni Nádábù, Ábíhù, Élíásérì àti Ítamárì Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ Bẹ́ẹ̀ ni Élíásérì àti Ítamárì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ṣádókì ọmọ Élíásérì àti Áhímélékì ọmọ Ítamárì, Dáfídì sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Élíásérì ju lára àwọn ọmọ Ítamárì lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ mẹ́rindínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Élíásérì ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Ítamárì Wọ́n sì pín wọn lótìítọ́ nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olorí ilé Ọlọ́run wà láàrin àwọn ọmọ méjèèjì Élíásérì àti Ìtamárì Ṣémáíà ọmọ Nétanélì, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Léfì sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè Ṣádókù Àlùfáà, Áhímélékì ọmọ Ábíátarì àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Éléásári àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Ítamárì Ìpín èkíní jáde sí Jéhóíáríbù, èkejì sí Jédáià, Ẹlẹ́kẹta sì ni Hárímù, ẹ̀kẹ́rin sì ní Ṣéórímù, Ẹ̀karùn-ún sì ni Maíkíyà, ẹlẹkẹ́fà sì ni Míjámínì, Ẹ̀kẹ́je sì ni Hakósì, ẹlẹ́kẹ́jọ sí ni Ábíjà, Ẹkẹ́sàn sì ni Jésúà, ẹ̀kẹ́wà sì ni Ṣékáníà, Ẹ̀kọ́kànlá sì ni Élíásíbù, ẹlẹ́kẹjìlá sì ni Jákímù, Ẹ̀kẹtàlá sì ni Húpà, ẹlẹ́kẹrìnlá sì ni Jéṣébéábù, Ẹkẹdógun sì ni Bílígà, ẹ̀kẹ́rìndílogún sì ni Ímerì Ẹ̀kẹtàdílógún sì ni Héṣírì, ekejìdílógún sì ni Háfísesì, Ẹ̀kọkàndílógún sì ni Pétalà, ogún sì ni Jéhésékélì, Ẹ̀kọ́kànlélógún sì ni Jákínì, ẹ̀kẹ́rìnlélogún sì ni Gámúlì, Ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Déláyà, ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Másíà Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé Olúwa , gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Árónì gẹ́gẹ́ bí Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí pàṣẹ fun wọn Ìyòókù àwọn ọmọ Léfì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámúríamù Ṣúbáelì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣúbáélì Jédeíà Àti gẹ́gẹ́ bí Réhábíà, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Réhábíà Íṣíà sì ni alákọ́kọ́ Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Iṣárì Ṣélómótì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣélomótì Jáhátì Àwọn ọmọ Hebúrónì Jéríyà alákọ́kọ́, Ámáríyà elẹ́kẹjì, Jáhásélì ẹlẹ́kẹta àti Jékáméámù ẹlẹ́kẹrin Àwọn ọmọ Húsíélì Mikà nínú àwọn ọmọ Míkà Ṣámírù Àwọn arákùnrin Míkà Íṣíà nínú àwọn ọmọ Íṣíà Ṣekaríyà Àwọn ọmọ Mérarì Málì àti Múṣì Àwọn ọmọ Jásíà Bẹ́nò Àwọn ọmọ Mérárì Lati Jasíà Bẹ́nò, Ṣóhámù, Ṣákúrì àti Íbírì Láti Málì Élíásérì, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ Láti Kíṣì Àwọn ọmọ Kíṣì Jérámélì Àti àwọn ọmọ Muṣì Málì, Édérì àti Jérímotì Èyí ni àwọn ọmọ Léfì, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Árónì ṣe ṣẹ́, níwáju ọba Dáfídì àti Ṣádókì, Áhímélékì, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì Àwọn ìdilé àgbààgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arakùnrin wọn kéékèèkéé Àwọn Akọrin Pẹ̀lúpẹ̀lú Dáfídì àti àwọn olórí àwọn ọmọ ogun, ó sì yà díẹ̀ sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì fún ìsìn àsọtẹ́lè, pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin àti kínbálì Èyí sì ní àwọn iye àwọn ọkùnrin ẹni tí ó ṣe oníṣẹ́ ìsìn yìí Nínú àwọn ọmọ Ásáfù Ṣákúrì, Jóṣẹ́fù Nétanáíà àti Ásárélà, àwọn ọmọ Ásáfù ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó Ásáfù, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ ìbojútó ọba Gẹ́gẹ́ bí ti Jédútúnì, nínú àwọn ọmọkùnrin Rẹ̀ Gédálià, Ṣérì, Jéṣáíà, Ṣíméhì Háṣábíà àti Mátítíyà, mẹ́fà nínú gbogbo wọn, lábẹ́ ìbojútó baba wọn Jédútúnì, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ó lo dùùrù láti dúpẹ́ àti lati yin Olúwa Gẹ́gẹ́ bí ti Hémánì, nínú àwọn ọmọ Rẹ̀ Búkíà, Mátaníyà, Usíélì, Ṣúbáélì àti Jérímótì Hánáníyà, Hánánì, Élíátà, Gídáítì àti Rámámútì Ésérì Jósíbékáṣà, Málótì, Hótírì àti Máhásíótì Gbogbo àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Hémánì àti wòlíì ọba Wọ́n sì fi wọ́n fún nípa ìlérí Ọlọ́run láti máa gbé ìwo sókè Ọlọ́run sì fún Hémánì ní ọmọkùnrin mẹ́rìnlá àti àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó àwọn bàba wọn fún ohun èlò orin ilé Olúwa , pẹ̀lú Kínbálì, Písálítérì àti dùùrù, fún Ìsìn ilé Olúwa Ásáfù, Jédútúnì, ọba Àwọn ìdilé wọn pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó mòye àti àwọn tí a kọ́ ní ohun èlò orin fún Olúwa , iye wọn sì jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́jọ Kékeré àti àgbà bákan náà, olùkọ́ àti gẹ́gẹ́ bí ti ọmọléèwé, pin dànù fún isẹ́ wọn Isẹ́kèké èkíni èyí tí ó jẹ́ ti Ásáfù, jáde sí Joṣéfù, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ jẹ́, méjìlá ekejì sì ni Gédálíà, òun àti àwọn ìdílé Rẹ̀ àti àwọn ọmọ Rẹ̀, méjìlá ẹlẹ́kẹ́ta sí Sákúrù, àwon ọmọ Rẹ̀ àti àwon ìdílé, méjìlà ẹlẹ́kẹrin sí Ísírì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwon ìdílé Rẹ̀ jẹ́, méjìlá ẹlẹ́karùnún sí Nàtania, àwon ọmọ Rẹ̀ àti àwon ìdílé rè jẹ́, méjìlá ẹlẹ́kẹfà sí Búkíà, àwon ọmọ Rẹ̀ àti àwọn ìdílé Rẹ̀ jẹ́, méjìlá ẹlẹ́keje sí Jésárélà, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti Àwọn ìdílé Rẹ̀ jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ sí Jéṣáíáyà, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwọn ìdílé Rẹ̀ jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kẹ́sàn-án sí Mátaníáyà, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwon ìdílé Rẹ̀ jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kẹ́wàá sí Síméì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwon ìdílé Rẹ̀ jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kọkànlá sí Ásárélì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwọn ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kẹjìlá sí Hásábíà, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlá sí Ṣúbáélì, àwọn ọmọ Rẹ̀ Àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kẹrìlá sí Mátítaíà, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kẹdógún sí Jérímótì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndílógún sí Hananáì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kẹtàdílógún sí Jóṣíbákásà, àwọn ọmọ Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kejìdílógún sí Hánánì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kọkàndílógún sí Míólítì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ogún sí Élíátà, awọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kọkànlélógún sí Hótírì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwọn ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kejìlélógún sí Gídálì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwọn ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ẹlẹ́kẹtalélógún sí Máhásíotì, àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá ẹlẹ́ẹ̀kẹ́rìnlélógún sí Rómátì-Ésérì, àwọn ọmọ Rẹ̀, àti àwọn ìdílé Rẹ̀, sì jẹ́, méjìlá Àwọn Olùtọ́jú Ẹnu Ọ̀nà Àwọn ìpín tí àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà Láti ọ̀dọ̀ Kórà Méṣélémíò ọmọ Kórè, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Áṣáfì Méṣélémíà ní àwọn ọmọkùnrin Ṣékáríáyà àkọ́bí, Jédíáélì ẹlẹ́ẹ̀kejì, Ṣébádíáyà ẹlẹ́ẹ̀kẹta, Játiníẹ́lì ẹlẹ́ẹ̀kẹ́rin, Élámù ẹlẹ́ẹ̀kaàrún, Jehóhánánì ẹlẹ́ẹ̀kẹfà àti Eliéhóémáì ẹlẹ́ẹ̀keje Obedi-Édómù ni àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú Ṣémáíà àkọ́bí, Jéhóṣábádì ẹlẹ́ẹ̀kejì, Jóà ẹlẹ́ẹ̀kẹta, Ṣákárì ẹlẹ́ẹ̀kẹrin, Nétanélì ẹlẹ́ẹ̀kaàrún, Ámíélì ẹ̀kẹfà, Ísákárì ẹ̀keje àti péúlétaì ẹ̀kẹjọ Ọmọ Rẹ̀ Ṣémáíà ní àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé bàbá a wọn nítorí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tó lágbára Àwọn ọmọ Ṣémáíà Ótínì, Refáélì, Óbédì àti Élíṣábádì àwọn ìbátan Rẹ̀ Élíhù àti Sémákíà jẹ́ ọkùnrin alágbára Gbogbo wọ̀nyí ní ìran ọmọ Obedi Édómù àwọn àti ọmọkùnrin àti ìbátan wọn jẹ́ alágbára ọkùnrin pẹ̀lú ipá láti ṣe ìsìn náà Àtẹ̀lé Obedi Édómù méjìlélọ́gọ́ta ni gbogbo Rẹ̀ Móésélémíà ní àwọn ọmọ àti àwọn ìbátan, tí ó jẹ́ alágbára méjìdínlógún ni gbogbo wọn Hósà ará Merà ní àwọn ọmọkùnrin Ṣímírì alákọ́kọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé kì i se àkọ́bí, baba a Rẹ̀ ti yàn an ní àkọ́kọ́ Hílíkíyà ẹlẹ́ẹ̀kejì, Tábálíà ẹ̀kẹta àti Ṣékárià ẹ̀kẹrin, àwọn ọmọ àti ìbátan Hósà jẹ́ mẹ́talá ni gbogbo Rẹ̀ Ìpín wọ̀nyí ti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà nípasẹ̀ olóyè ọkùnrin wọn, ní iṣẹ́ ìsìn fún jíjísẹ́ nínú ilé Olúwa , gẹ́gẹ́ bí ìbátan wọn ti ṣe Wọ́n ṣẹ́ kèké fún ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ìdílé wọn bí ọ̀dọ́ àti arúgbó Kèké fún ẹnu ọ̀nà ilà oòrùn bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣélémíáyà, nígbà náà a dá kèké fún ọmọkùnrin rẹ̀ Ṣekaríáyà, ọlọ́gbọ́n onímọ̀ràn, kèké fún ẹnu ọ̀nà àríwá sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ Kèké fún ẹnu ọ̀nà ìhà gúṣù bọ́ sí ọ̀dọ̀ Obedì Édómù, kèké fún ilé ìṣúra sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ ọmọ Rẹ̀ Kèké fún ẹnu ọ̀nà ìhà ìwọ̀ oòrùn àti Ṣálélà-etí ẹnu ọ̀nà ní ọ̀nà apá òkè bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣúpímì àti Hósà Olùsọ́ wà ní ẹ̀bá Olùsọ́ Àwọn ará Léfì mẹ́fà ní ó wà ní ọjọ́ kan ní ìhà ìlà oòrùn, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà àríwá, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà gúṣù àti méjì ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ilé ìṣúra Ní ti ilé ẹjọ́ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, mẹ́rin sì wà ní ojú ọ̀nà àti méjì ní ilé ẹjọ́ fúnrarẹ̀ Wọ̀nyí ni ìpín ti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà tí wọ́n jẹ́ àwọn ìran ọmọ ti kórà àti Mérà Àwọn ẹlẹ́gbẹ́ Léfì wọn wà ní ìdí ilé ìfowópamọ́ sí ti ile Ọlọ́run àti ilé ohun èlò yíyà sọ́tọ̀ Àwọn ìran ọmọ Ládánì tí wọn jẹ́ ará Géríṣónì nípaṣẹ̀ Ládánì àti tí wọn jẹ́ àwọn olorí àwọn ìdílé tí ó jẹ́ ti Ládánì ará Gérísónì ni Jehíélì, Àwọn ọmọ Jehíélì, Ṣétámì àti arákùnrin Rẹ̀ Jóélì Wọ́n ṣalábojútó ilé ìṣúra ti ilé ìṣúra ti ilé Olúwa Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Ámírámù, àwọn ará Íṣíhárì, àwọn ará Hébírónì àti àwọn ará Úṣíélì Ṣúbáélì, ìran ọmọ Gérísómì ọmọ Mósè jẹ́ oníṣẹ́ tí ó bojútó ilé ìṣúra Àwọn ìbátan Rẹ̀ nípaṣẹ̀ Élíeṣérì Réhábíà ọmọ Rẹ̀, Jéṣáíà ọmọ Rẹ̀, Jórámì ọmọ Rẹ̀ Ṣélómítì àti àwọn ìbátan Rẹ̀ jẹ́ alábojútó ilé ìṣúra fún àwọn ohun tí à ti yà sọ́tò nípa ọba Dáfídì, nípaṣẹ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ alákóso ọrọrún àti nipaṣẹ̀ alákóṣo ọmọ-ogun mìíràn Díẹ̀ nínú ìkógun tí wọ́n kó nínú ogun ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún títún ilé Olúwa ṣe Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ṣámúẹ́lì aríranl àti nípasẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, Ábínérì ọmọ Nerì àti Joábù ọmọ Ṣeruíà gbogbo ohun tí a yà sọ́tọ̀ sì wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣélómítì àti àwọn ìbátan Rẹ̀ Láti ọ̀dọ̀ àwọn Iṣíhárì Kénáníà àti àwọn ọmọ Rẹ̀ ni a pín iṣẹ́ ìsìn fún kúrò ní apá ilé Olúwa , gẹ́gẹ́ bí àwọn onísẹ́ àti àwọn adájọ́ lórí Ísirẹ́lì Láti ọ̀dọ̀ àwọn Hébírónì Háṣábíà àti àwọn ìbátan Rẹ̀ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀san ọkùnrin alágbára ní ó dúró ni Ísírẹ́lì, ìhà ìwọ̀ oòrùn Jórólánì fún gbogbo iṣẹ́ Olúwa àti fún iṣẹ́ ọba Níti àwọn ará Hébírónì, Jéríyà jẹ́ olóyè wọn gẹ́gẹ́ bí ìwé ìrántí ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn ní ti ìdílé wọn Ní ọdún kẹrin ìjọba Dáfídì, a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí, àwọn ọkùnrin alágbára láàrin àwọn ará Hébíronì ni a rí ní Jáṣérì ní Gílíádì Jéríyà ní ẹgbàáméjì, àti ọgọ́rin méje ìbátan, tí wọn jẹ́ ọkùnrin alágbára àti olórí àwọn ìdilé ọba Dáfídì sì fi wọ́n ṣe àkóso lórí àwọn ará Reúbẹ́nì àwọn ará Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Mánásè fun gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó jọ mọ́ ti Ọlọ́run àti fún ọ̀ràn ti ọba Ìpín Ti Àwọn Ọmọ Ogun Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọrọrún àti àwọn ìjòyè wọn Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣoṣù ní gbogbo ọdún Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ólé ẹgbàá mẹ́rin ọkùnrin Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ni fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jáṣóbéámù ọmọ Ṣábídiélì àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ólé ẹgbàá mẹ́rin ní ó wà ní abẹ́ ìpín tirẹ̀ Ó jẹ́ ìran ọmọ pérésì àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dódáì ará Áhóhì Míkílótì jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀ Ọkùnrin ẹgbàá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀ Olórí àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Bénáyà ọmọ Jéhóíádà àlùfáà Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ní ó wà ní ìpín tirẹ̀ Èyí ni Bénáyà náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrin àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n Ọmọ Rẹ̀ Ámíṣábádì jẹ́ alákóso lórí ìpín tirẹ̀ Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Ásáhélì arákùnrin Jóábù ọmọ Rẹ̀ Ṣébádáyà jẹ́ arọ́pò Rẹ̀ Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin ni ó wà ní ìpín Rẹ̀ Ẹ̀káàrún fún oṣù kárùn-ún, jẹ́ olórí Ṣámíhútì ará Íṣíráhì Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin ní ó wà ní ìpín tirẹ̀ Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Írà ọmọ Íkéṣì, ará Tékóì Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín Rẹ̀ Ẹ̀kéje fún oṣù kéje jẹ́ Hélésì ará Pélónì, ará Éfíráímù Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni o wà ní ìpín Rẹ̀ Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Ṣíbékáì ará Húṣátì, ará Ṣéráhì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín Rẹ̀ Ẹ̀kẹsàn-án fún oṣù kẹ́sàn-án jẹ́ Ábíésérì ará Ánátótì, ará Bénjámínì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín Rẹ̀ Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹ́wàá jẹ́ Máháráì ará Nétófátì, ará Ṣéráhì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín Rẹ̀ Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Bénáyà ará pírátónì ará Éfíráímù ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀ Ìkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Hélídáì ará Nétófátì láti ìdílé Ótíníélì Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin ni ó wà ní ìpín tirẹ̀ Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Ísírẹ́lì lórí àwọn ará Réúbẹ́nì Éliésérì ọmọ Ṣíkírì lórí àwọn ará Ṣíméónì Ṣéfátíyà ọmọ Mákà lórí Léfì Háṣábíà ọmọ Kémúélì lori Árónì Ṣádókù lórí Júdà Élíhù arákùnrin Dáfídì lóri Ísákárì Ómírì ọmọ Míkáélì lórí Ṣébúlúnì Íṣímáíà ọmọ Óbádáyà lori Náfitalì Jérímótì ọmọ Áṣíríélì lórí àwọn ará Éfíráímù Hòṣéà ọmọ Áṣásíà lorí ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè Jóélì ọmọ Pedáyà lorí ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní Gílíádì Ìdó ọmọ Ṣékáráyà lórí Bẹ́ńjámínì Jásíélì ọmọ Ábínérì lórí Dánì Áṣárélì ọmọ Jéróhámù Wọ̀nyí ni àwọn ìjòyè lórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì Dáfídì kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítori Olúwa ti ṣe ìlerí lati ṣe Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run Jóábù ọmọ Ṣérúyà bẹ̀rẹ̀ sí ní kàwọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Ísírẹ́lì nipaṣẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọọ́ sínu ìwé ìtàn ayé ti ọba Dáfídì Áṣímáfétì ọmọ Ádíélì wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba Jónátanì ọmọ Úṣíà wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìlètò àti àwọn ilé ìṣọ́ Ésírì ọmọ kélúbì wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà Ṣíméhì ará Rámátì wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà Ṣábídì ará Ṣífímì wà ní ìdí mímú jáde ti èṣo àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí Bálì Hánánì ará Gédérì wà ní ìdi Ólífì àti àwọn igi Ṣíkámórè ní apá ìhà ìwọ̀ oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jóáṣì wà ní ìdí fífún ni ní òróró Ólífì Ṣítíráì ará Ṣárónì wà ní idi fífi ọwọ́ ẹran jẹ ko ní Ṣárónì Ṣáfátì ọmọ Ádíláì wà ní ìdí àwọn ọ̀wọ́-ẹran ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ Óbílì ará Íṣímáélì wà ní ìdí àwọn ìbákasíẹ Jéhidéísì ará Mérónótì wà ní ìdí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Jáṣíṣì ará Hágírì wà ní ìdi àwọn agbo-ẹran Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wà ní ìdí ẹrù ọba Dáfídì Jónátanì, arákùnrin Dáfídì jẹ́ olùdámọ̀ràn, ọkùnrin onímọ̀ àti akọ̀wé Jéhíélì ọmọ Hákímónì bojútó àwọn ọmọ ọba Áhítófélì jẹ́ olùdámọ̀ràn ọba Húsáì ará Áríkì jẹ́ ọ̀rẹ́ ọba Jéhóíádà ọmọ Bẹnáyà àti nípaṣẹ̀ Ábíátárì jọba rọ́pò Áhítófélì Jóábù jẹ́ olórí ọmọ ogun ọba Àwọn Èrò Dáfídì Lórí Ilé Dáfídì pe gbogbo àwọn oniṣẹ́ ti Ísírẹ́lì láti pẹ́jọ ní Jérúsálẹ́mù Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà, àwọn alákòóṣo ìpín nínú iṣẹ́ bí ọba, àwọn alákòóṣo ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóṣo ọrọrún àti àwọn onísẹ́ tí ó wà ní ìdí bíbojútó gbogbo àwọn ẹrù àti ohun ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti ọba àti àwọn ọmọ Rẹ̀ pẹ̀lú ààfin àwọn onísẹ́ ààfin, àwọn ọkùnrin alágbára àti gbogbo àwọn ògbójú jagunjagun lápapọ̀ Ọba Dáfídì dìde dúró ní ẹṣẹ̀ Rẹ̀, o sì wí pé Fetísílẹ̀ sí mi, ẹyin ará mi àti ẹ̀yin ènìyàn mi Èmi ní o ni ọkàn mi láti kọ́ ilé gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi fún àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú tí Olúwa fún àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run wa, èmi sì gbèrò láti kọ́ ọ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún mi pé Ìwọ kò gbodò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ jẹ́ jagunjagun, ìwọ sì ti tàjẹ̀sílẹ̀ Síbẹ̀ Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì yàn mí láti gbogbo ìdílé láti jẹ́ ọba lórí Ísírẹ́lì, títí láé Ó yan Júdà gẹ́gẹ́ bí olórí, àti láti ilé Júdà, ó yan ìdílé mi, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ baba à mí, ó tẹ́ Ẹ lọ́rùn láti fi mí ṣe ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì Ninú gbogbo àwọn ọmọ mi pẹ̀lú Olúwa ti fún mi ní púpọ̀, ó ti yan ọmọ mi Sólómónì láti jòkó lórí ìtẹ́ ìjọba ti Olúwa lóri Isírẹ́lì Ó wí fún mi pé, Sólómónì ọmọ rẹ ni ẹni tí yóò kọ́ ilé mi àti àwọn ààfin mi, Nítorí tí èmi ti yàn án láti ṣe ọmọ mi èmi yóò sì jẹ́ baba a Rẹ̀ Èmi yóò fi ìdí ìjọba Rẹ̀ kalẹ̀ títí láé tí kò bá kọ̀ láti gbé àṣẹ àti òfin mi jáde, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe é ní àsìkò yìí Bẹ́ẹ̀ ni, nísinsìn yìí, èmi pàṣẹ fún ọ ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì àti ní ti ìpéjọpọ̀ tí Olúwa , àti ní etí ìgbọ́ Ọlọ́run wa Ṣọ́ra kó o sì tẹ̀lé gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run rẹ kí ìwọ kí ó le jogún ilẹ̀ dáradára yìí, kí o sì mú un lọ síwájú gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ fún àwọn ìran ọmọ rẹ títí láé Àti ìwọ, ọmọ mi Sólómónì, rántí Ọlọ́run baba à rẹ, kí o sì sìn-ín pẹ̀lú tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfọkànsí pẹ̀lú ọkàn tí ó pé, nítorí Olúwa ṣàwárí gbogbo ọkàn ó sì mọ gbogbo èrò Tí ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ọ́ títí láé Gbèrò báyìí nítorí tí Olúwa ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí ilé tí a yà sí mímọ́ fún Olúwa Jẹ́ alágbára kí ó sì ṣe iṣẹ́ náà Nígbà náà, Dáfídì fún Sólómónì ọmọ Rẹ̀ ní ètò fún èbúté ilé Olúwa náà, kíkọ́ ọ Rẹ̀, àwọn yàrá ìṣúra Rẹ̀, ibi òkè Rẹ̀, àwọn ìyẹ̀wù Rẹ̀ àti ibi ìpètù sí Rẹ̀ Ó fún un ní àwọn ètò gbogbo èyí tí ẹ̀mí ti fi sí ọkàn Rẹ̀ fún ti ààfin ilé Olúwa àti gbogbo yàrá tí ó yíká fún ìṣúra ilé Ọlọ́run àti fún ìṣúra fún ohun yíyà sọ́tọ̀ Ó fún un ní àwọn ìlànà fún ìpín ti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àti fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa àti fún gbogbo ohun èlò tí wọn ó lò nínú ìsìn Rẹ̀ Ó yàn ìwọ̀n wúrà fún gbogbo ohun èlò wúrà tí a ó lò níbi orísìí ìsìn, àti ìwọ̀n fàdákà fún gbogbo ohun èlò fàdákà tí a ó lò fún oríṣìí ìsìn Ìwọ̀n wúrà fún ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn, fún ìwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn àti ìwọ̀n fàdákà ìdúró fìtilà fàdákà àti àwọn fìtílà Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlò ti gbogbo ìduró fìtílà Ìwọ̀n ti wúrà fun tabílì, tabílì fún àkàrà tí a yà sọ́tọ̀ ìwọ̀n fàdákà fún àwọn tábìlì fàdákà Ìwọ̀n kìkìdá wúrà fún àwọn àmúga ìjẹun, àwọn ìbùwọ̀n ọpọ́n àti àwọn ìkòkò ìpọnmi Ìwọ̀n wúrà fún gbogbo àwo pọ̀ọ́kọ̀ fàdákà Àti ìwọ̀n ìdá wúrà fún Pẹpẹ tùràrí ó fún un ní ètò fún kẹ̀kẹ́, ìyẹn ni pé àwọn ìdúró kérúbù wúrà tí wọ́n tan iye wọn ká, wọ́n sì bo àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa Gbogbo èyí, ni Dáfídì wí pé, Èmi ní kíkọ sílẹ̀ láti ọwọ́ Olúwa sórí mi, ó sì fún mí ní ìmọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ ètò yìí Dáfídì tún sọ fún Sólómónì ọmọ Rẹ̀ pé, Jẹ́ alágbára kí o sì gbóyà, kí o sì ṣe isẹ́ náà Má ṣe bẹ̀rù tàbí dààmú, nítorí Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run mi, wà pẹ̀lú rẹ Òun kì yóò sì jọ ọ kule tàbí kọ Ọ sílẹ̀ títí gbogbo iṣẹ́ fún ìsìn ní ti ilé Olúwa yóò fi parí Ìpín àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì ti ṣetan fún gbogbo iṣẹ́ ilé Olúwa Gbogbo ọkùnrin tí ó ní ìfẹ́ sí i tí ó sì ní òye oríṣìíríṣìí iṣẹ́ Yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà Àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn ènìyàn yóò gbọ́ràn sí gbogbo àṣẹ rẹ Ẹ̀bùn Fún Kíkọ́ Ilé Nígbà náà, ọba Dáfídì sọ fún gbogbo àpéjọ pé Ọmọ mi Sólomónì, èyí tí Ọlọ́run ti yàn, ṣì kéré ó sì jẹ́ aláìmòye Iṣẹ́ náà tóbi, nítorí ìkọ́lé bí ti ààfin kì í ṣe fún ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa Ọlọ́run Pẹ̀lu gbogbo ìrànlọ́wọ́ mi èmi ti pèsè fún ilé Ọlọ́run mi wúrà fún iṣẹ́ wúrà, fàdákà fún ti fàdákà, òjíá fún ti òjíá, irin fún ti irin àti igi fún ti igi àti òkúta oníyebíye fún títọ́ Rẹ̀, òkúta lóríṣíríṣí, àmọ̀ àti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà òkúta àti òkuta dáradára kan gbogbo wọ̀nyí ní iye púpọ̀ Yàtọ̀ fún èyí, nínú ìfọkànsìn mi sí ilé Ọlọ́run mi, èmí fi ìṣúra mi tìkalára mí ti wúrà àti fàdákà fún ilé Ọlọ́run mi, jù gbogbo Rẹ̀ lọ, èmi ti pèṣè fún ilé mímọ́ ti Olúwa yìí Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta talẹ́ntì wúrà àti ẹgbẹ̀rin méje tálẹ́ntì fàdákà tí a yọ̀rọ̀ kúrò, fún bíbo àwọn ògiri ilé náà Fún iṣẹ́ wúrà àti fàdákà náà, àti fún orísìí iṣẹ́ ti ó yẹ ní ṣíṣe nípaṣẹ̀ àwọn tí ó ní òye oríṣíiríṣí iṣẹ́ Níṣinṣìn yìí, ta ni ó ní ìfẹ́ sí yíya ará Rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí sí Olúwa Nígbà náà àwọn aṣájú àwọn ìdílé, àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, àwọn alákòóṣo ẹgbẹgbẹ̀wá àti alákòóṣo ọrọrún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí iṣẹ́ ọba ní ìfẹ́ sí i Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún talẹ́ntì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá talẹ́ntì fàdákà, ẹgbẹ̀rin méjìdínlógún talẹ́ntì òjíá àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin talẹ́ntì irin Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Ọlọ́run ní ìhámọ́ Jéhíélì ará Géríṣónì Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí Olúwa Dáfídì ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi Dáfídì yin Olúwa níwájú gbogbo àwọn tí ó péjọ, wí pé, Ìyìn ni fún Ọ, Olúwa , Ọlọ́run baba a wa Ísírẹ́lì, láé àti láéláé Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn àti ọlá ńlá àti dídán, nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ Tìrẹ Olúwa ni ìjọba a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti láti fi agbára fún ohun gbogbo Nísinsìn yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ, a sì fi ìyìn fún orúkọ Rẹ̀ tí ó lógo Ṣùgbọ́n Ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè fi sílẹ̀ tinútínú bí irú èyí Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ Àwa jẹ́ àjèjì àti àlejò ní ojú rẹ gẹ́gẹ́ bí baba ńlá a wa, àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé rí bí òjìji láìsí ìrètí Olúwa Ọlọ́run wa tí fi gbogbo pípọ̀ yìí tí àwa ti pèṣè fún kíkọ́ ilé Olúwa fun orúkọ, mímọ́ Rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo Rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀ Èmi mọ̀ Ọlọ́run mi, wí pé ìwọ̀ dán ọkàn wò, ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn pẹ̀lú òtítọ́ inú Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́ pẹ̀lú òtítọ́ Nísinsìn yìí èmi ti ríi pẹ̀lú ayọ̀ bí àwọn ènìyàn yìí tí ó wà níbí ti fi fún ọ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wa Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì pa ìfẹ́ yìí mọ́ ninú ọkàn àwọn ènìyàn rẹ títí láé pẹ̀lú pípa ọkàn mọ́ lóòtọ́ sí ọ Àti fún ọmọ mi Sólómónì ní ìfọkànsìn tòótọ́ láti pa àṣẹ rẹ mọ́ àwọn ohun tí ó nílò àti òfin àti láti ṣe ohun gbogbo láti kọ́ ààfin bí ti ọba fún èyí tí mo ti pèsè Dáfídì sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn pé, Nísinsìn yìí, ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín Gbogbo ènìyàn sì fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì tẹ orí wọn ba, wọ́n wólẹ̀ fún Olúwa àti ọba Ni ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa , wọ́n sì rú ẹbọ ọrẹ ṣíṣun sí i ẹgbẹ̀rún kan akọ màlúù, ẹgbẹ̀rin kan àgbò, àti ẹgbẹ̀rin kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn Lápapọ̀ pẹ̀lú ọrẹ mímu àti àwọn ẹbọ mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì Wọ́n jẹ wọ́n sì mu pẹ̀lú ayọ̀ kíkún ní iwájú Olúwa ní ọjọ́ náà Nígbà náà wọ́n yan Sólómonì ọmọ Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́ẹ̀kejì wọ́n fi àmì òróró yàn án níwájú Olúwa láti ṣe olórí àti Ṣádókù láti ṣe àlùfáà Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò bàbá a Rẹ̀ Dáfídì O ṣe àṣeyọrí, gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu Gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn ọkùnrin alágbára, pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọba Dáfídì tẹrí ara wọn ba fún ọba Sólómónì Olúwa gbé Solómónì ga púpọ̀ ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì kẹ́ ẹ ní ìkẹ́ ọlá ńlá, ní irú èyí tí a kò kẹ́ ọba kankan ṣáájú Rẹ̀ tí ó jẹ lórí Ísírẹ́lì Dáfídì ọmọ Jéṣè jẹ́ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì Ó jọba lórí Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún ọdún méje ni ó jọba ní Hẹ́súrónì, ó sì jọba ní ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n ní Jérúsálẹ́mù Òun sì darúgbó, ó sì kú ikú rere, ó gbádùn ẹ̀mí gígùn, ọlá àti ọrọ̀ Sólómónì ọmọ Rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀ Ní ti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba ọba Dáfídì, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, a kọ wọ́n sínú ìwe ìrántí ti Sámúẹ́lì aríran, ìwé ìrántí ti Nátanì wòlíì àti ìwé ìrántí ti Gádì aríran, lápapọ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti agbára Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbà tí ó kọjá lórí Rẹ̀, àti lórí Ísírẹ́lì, àti lórí gbogbo àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ náà Àwọn ọmọ Dáfídì Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dáfídì tí a bí fún un ní Hébírónì Àkọ́bí sì ni Ámínónì ọmọ Áhínóámù ti Jésírẹ́lì èkejì sì ni Dáníẹ́lì ọmọ Ábígáílì ará Kárímélì Ẹ̀kẹta sì ni Ábúsálómù ọmọ Mákà ọmọbìnrin ti Táímáì ọba Gésúrì ẹ̀kẹrin sì ni Àdóníjà ọmọ Hágítì Ẹ̀kárùnún ni Ṣéfátíyà ọmọ Ábítalì àti ẹ̀kẹfà, Ítíréàmù, láti ọ̀dọ̀ ìyàwó Rẹ̀ Égílà Ẹ̀kẹfà ni a bí fún Dáfídì ni Hébúrónì, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà Dáfídì sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un Ṣámúyà, Ṣóbábù, Náhátì àti Sólómónì Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bátíṣébà ọmọbìnrin Ámíélì Íbíhárì sì wà pẹ̀lú, Élíṣúà, Élífélétì, Nógà, Néfégì, Táfíà, Élísámù, Élíádà àti Élífétélì mẹ́sàn án ni wọ́n Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dáfídì yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un Támárì sì ni arábìnrin wọn Ọmọ Sólómónì ni Réhóbóhámù, Ábíjà ọmọ Rẹ̀, Ásà ọmọ Rẹ̀, Jéhósáfátì ọmọ Rẹ̀, Jéhórámù ọmọ Rẹ̀, Áhásáyà ọmọ Rẹ̀, Jóásì ọmọ Rẹ̀, Ámásáyà ọmọ Rẹ̀, Ásáríyà ọmọ Rẹ̀, Jótamù ọmọ Rẹ̀, Áhásì ọmọ Rẹ̀, Hesekíáyà ọmọ Rẹ̀, Mánásè ọmọ Rẹ̀, Ámónì ọmọ Rẹ̀, Jósíà ọmọ Rẹ̀ Àwọn ọmọ Jósíà Àkọ́bí ọmọ Rẹ̀ ni Jóhánánì, èkejì ọmọ Rẹ̀ ni Jéhóíákímù, ẹ̀kẹta ọmọ Rẹ̀ ni Ṣédékíà, ẹ̀kẹ́rin ọmọ Rẹ̀ ni Ṣálúmù Àwọn ìran ọmọ Jéhóíákímù Jékóníà ọmọ Rẹ̀, àti Ṣedékíà Àwọn ọmọ Jéhóíákímù tí a mú ní ìgbékùn Ṣálátíélì ọmọ Rẹ̀ ọkùnrin, Málíkírámù, Pédáíyà, Ṣénásárì, Jékámíà, Hósámà àti Nédábíà Àwọn ọmọ Pédáíyà Ṣérúbábélì àti Ṣíméhì Àwọn ọmọ Ṣérúbábélì Mésúlámù àti Hánáníyà, Ṣélómítì ni arábìnrin wọn Àwọn márùnún mìíràn sì tún wà Hásúbà, Óhéhì, Bérékíà, Hasádíà àti Jusabi-Hésédì Àwọn ọmọ Hánáníyà Pélátíà àti Jeṣáíà, àti àwọn ọmọ Réfáíà, ti Árínánì, ti Ọbadíà àti ti ṣékáníà Àwọn ọmọ Ṣékáníà Ṣémáíà àti àwọn ọmọ Rẹ̀ Hátúsì, Ígéálì, Báríà, Néáríà àti Ṣáfátì, mẹ́fà ni gbogbo wọn Àwọn ọmọ Néáríà Élíóéníà Hísíkíà àti Ásírí kámù, mẹ́ta ni gbogbo wọn Àwọn ọmọ Élíóéníà Hódáíà, Élíásíbù, Pétéláéà, Ákúbù, Jóhánánì, Déláyà àti Ánánì, méje sì ni gbogbo wọn Òmíràn Ẹ̀yà Júdà Àwọn ọmọ Júdà Fárésì, Hésírónì, Kárímì, Húrì àti Ṣóbálì Réáíà ọmọ Ṣóbálì ni baba Jáhátì, àti Jáhátì baba Áhúmáyì àti Láhádì Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Ṣórà Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Étanílù Jésírélì, Ísímà, Ídíbásì, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Sélélípónì Pénúélì sì ni baba Gédórì, àti Édérì baba Húṣà Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Húrì, Àkọ́bí Éfúrátà àti baba Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Áṣárì bàbá Jékóà sì ní aya méjì, Hélà àti Nárà Nárà sì bí Áhúsámù, Héférì Téménì àti Háhásítarì Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Nátà Àwọn ọmọ Hélà Ṣérétì Ṣóárì, Étanì, Àti kósì ẹnítí ó jẹ́ baba Ánúbì àti Hásóbébà àti ti àwọn Ẹ̀yà Áháríhélì ọmọ Hárúmù Jábésì sì ní olá ju àwọn ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ ọkùnrin lọ Ìyá Rẹ̀ sì sọ ọ́ ní Jábésì wí pé, Mo bí i nínú ìpọ́njú Jábésì sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, Áà, Ìwọ yóò bùkún fún, ìwọ yóò sì mú agbégbé mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mí mọ́ kúrò nínú ibi kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ Rẹ̀ Kélúbù arákùnrin ṣúà, sì jẹ́ baba Méhírì, ẹni tí ó jẹ́ baba Ésítónì Ésítónì sì jẹ́ baba Bétí-ráfà, Páséà àti Téhína ti baba ìlú Náhásì Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Rékà Àwọn ọmọ Kénásì Otíníẹ́lì àti Ṣéráíà Àwọn ọmọ Ótiníẹ́lì Hátatì àti Méónótaì Méónótaì sì ni baba Ófírà Ṣéráíà sì jẹ́ baba Jóábù, baba Géhárásínù A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn onísọ́nà niwọ́n Àwọn ọmọ kálébù ọmọ Jéfúnè Irú, Élà, àti Námù Àwọn ọmọ Élà Kénásì Àwọn ọmọ Jéhálélélì Ṣífù, ṣífà, Tíríà àti Ásárélì Àwọn ọmọ Ésírà Jétẹ́rì, Mérédì, Éférì àti Jálónì Ọ̀kan lára àwọn aya Mérédì sì bí Míríámù, ṣámáì àti Íṣíbà baba Éṣítémóà Aya Rẹ̀ Jéhúdijà sì bí Jérédì baba Gédórì, Hébérì baba sókè àti Jékútíẹ́lì bàbá Sánóà Àwọn wọ̀nyí ni ọmọbìnrin ọmọ Bítíà ẹni ti Mérédì ti fẹ́ Àwọn ọmọ aya Hódíyà arábìnrin Náhámù Baba Kéílà ará Gárímì, àti Ésítémóà àwọn ará Mákà Àwọn ọmọ Símónì Ámónì, Rínà, Beni-Hánánì àti Tílónì Àwọn ọmọ Íṣì Ṣóhítì àti Beni-Sóhétì Àwọn ọmọ Ṣélà ọmọ Júdà Érì baba Lékà, Ládà baba Máréṣà àti àwọn ìdílé ilé àwọn tí ń wun aṣọ oníṣẹ́ ní Bẹti-Áṣíbéà Tókímù, ọkùnrin kósébà, àti Jóáṣì àti sáráfù, olórí ní Móábù àti Jáṣúbì Léhémù Àwọn sì ni amọ̀kòkò tí ń gbé ní Nítaímù àti Gédérà wọ́n sì dúró níbẹ̀ wọ́n sì ń sisẹ́ fún ọba Àwọn Ọmọ Síméónì Némúélì, Jámínì, Járíbì, Ṣérà àti Ṣáúlì Ṣálúmù sì jẹ́ ọmọ Ṣáúlì, Míbísámù ọmọ Rẹ̀ Miṣima ọmọ Rẹ̀ Àwọn ọmọ Míṣímà Hámúélì ọmọ Rẹ̀ Sákúrì ọmọ Rẹ̀ àti Ṣíméhì ọmọ Rẹ̀ Síméì sì ní ọmọkùnrin mẹ́rìndínlógún àti ọmọbìnrin mẹ́fà, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ ọkùnrin kò ní ọmọ púpọ̀ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìdílé wọn kò sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Júdà Wọ́n sì ń gbé ní Béríṣébà, Móládà, Hásárì Ṣúálì, Bílà, Ésémù, Tóládì, Bétúélì, Hórímà, Síkílágì, Bẹti máríkóbótì Hórímà Hásárì Ṣúsímù, Bẹti Bírì àti Ṣáráímì Àwọn wọ̀nyí ni ìlú wọn títí di ìgbà ọba Dáfídì, agbégbé ìlú wọn ni Étamù Háínì, Rímónì, Tókénì, Áṣánì àwọn ìlú márùnún Àti gbogbo ìletò tí ó wà ní agbégbé àti gẹ́gẹ́ bí ó ti dé Bálì Àwọn wọ̀nyí ni ibùgbé wọn, wọ́n sì pa ìwé ìtàn ìdílé mọ́ Méṣóbábù Jámilékì, Jóṣáì ọmọ Ámásáyà, Jóẹ́lì, Jéhù ọmọ Jósíbíà, ọmọ Ṣéráíáyà, ọmọ Ásíẹ́lì, Àti pẹ̀lú Élíóénáì, Jákóbà, Jéṣóháiyá, Ásáíyà, Ádíélì, Jésímíẹ́lì, Bénáíyà, Àti Ṣísà ọmọ ṣífì ọmọ Álónì, ọmọ Jédáíyà, ọmọ Ṣímírì ọmọ Ṣémáíyà Àwọn ọkùnrin tí a dárúkọ lókè yìí àwọn ni ìjòyè ìdílé wọn Àwọn ìdílé sì pọ̀ síi gidigidi, Wọ́n sì lọ sí ojú ọ̀nà Gédórì Lọ títí dé ìlà òrùn àfonífojì láti wá koríko fún àwọn agbo ẹran wọn Wọ́n sì rí koríko tútù tí ó dára ilẹ̀ náà gbòòrò ó sì ní àlàáfíà ó sì gbé jẹ́ Àwọn ará Ámù ni ó ń gbé bẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ Ọkùnrin tí a kọ orúkọ Rẹ̀ sókè wà ní ọjọ́ Hésékíà ọba Júdà àti àwọn ibùgbé wọn àti pẹ̀lú àwọn ará Máhúnì ẹni tí ó wà níbẹ̀ tí ó sì pa wọ́n run pátapáta Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ ẹ̀rí títí di òníyìí Nígbà náà wọ́n sì ń gbé ní iye wọn, nítorí pé koríko wà fún àwọn agbo ẹran wọn Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ará Síméónì, sin pẹ̀lú Pélátíà, Néáríà, Réfáíà àti Úsíélì, àwọn ọmọ Íṣì, gbógun sí àwọn òkè ìlú ti Ṣéírì Wọ́n sì pa àwọn ará Ámálékì tí ó kù àwọn tí ó ti sá lọ, wọ́n sì ti ń gbé bẹ̀ láti òní yìí Ìdílé Rúbẹ́nì Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àkọ́bí Ísírẹ́lì , àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àkọ́bí Ísírẹ́lì ni Hánókù àti Pálù, Hésirónì àti Kárímì Àwọn ọmọ Jóẹ́lì Ṣémáíà ọmọ Rẹ̀, Gógù ọmọ Rẹ̀, Ṣíméhì ọmọ Rẹ̀ Míkà ọmọ Rẹ̀, Réáíà ọmọ Rẹ̀, Báálì ọmọ Rẹ̀ Béérà ọmọ Rẹ̀, tí Tígílátì-pílínésérì ọba Ásíríà kó ní ìgbékùn lọ ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni òun jẹ́ Àti àwọn arákùnrin Rẹ̀ nípa ìdílé wọn, nígbà tí a ń ka ìtàn ìdílé ìran wọn Jélíélì àti Ṣékáríà ni olórí Àti Bélà ọmọ Ásásì ọmọ Ṣémà, ọmọ Jóẹ́lì tí ń gbé Áróérì àní títí dé Nébò àti Baaliméónì Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àti wọ ihà láti odo Yúfúrátè nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ si i ní ilẹ̀ Gílíádì Àti ní ọjọ́ Ṣọ́ọ̀lù, wọ́n bá àwọn ọmọ Hágárì jagun, ẹni tí ó ṣubú nípa ọwọ́ wọn wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ àríwá Gílíádì Àti àwọn ọmọ Gádì ń gbé ọ̀kánkán wọn, ní ilẹ̀ Básánì títí dé Sálíkà Jóẹ́lì olórí, Ṣáfámù ìran ọmọ, Jánáì, àti Ṣáfátì ni Básánì, Àti àwọn arákùnrin wọn ti ilẹ̀ àwọn baba wọn ní Míkáélì, Mésúlímù Ṣébà, Jóráì, Jákánì, Ṣíà àti Hébérì méje Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ábíháílì, ọmọ Húrì, ọmọ Járóà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Míkàẹ́lì, ọmọ Jésíháì, ọmọ Jádò ọmọ Búsì Áhì, ọmọ Ábídélì, ọmọ Gúnì, olórí ilé àwọn baba wọn Wọ́n sì ń gbé Gílíádì ní Básánì àti nínú àwọn ìlú Rẹ̀, àti nínú gbogbo ìgbéríko Sárónì, ní agbégbé wọn Gbogbo wọ̀nyí ni a kà nípa ìtàn-ìdílé, ní ọjọ́ Jótamù ọba Júdà, àti ní ọjọ́ Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àti àwọn ọmọ Gádì, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé aṣà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ènìyàn o le ẹgbẹ̀rinlélógún dín ogójì, tí ó jáde lọ sí ogún náà Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hágárì jagun, pẹ̀lú Jétúrì, àti Néfísì àti Nádábù Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hágárì lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn nítorí ti wọn képe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ ràkunmí ẹgbàámẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùnún, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbàá, àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn ún Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣubú tí a pa, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ogun náà, wọ́n sì jókòó ní ipò wọn títí di ìgbà ìkólọ sí ìgbékùn Àwọn ọmọkùnrin ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ń gbé ní ilẹ̀ náà wọ́n bí sí i láti Básánì títí dé Báálì-hérímónì, àti Ṣénírì àti títí dé òkè Hérímónì Wọ̀nyí sì ni àwọn olórí ilé àwọn baba wọn Éférì, Ísì, Élíélì, Ásíríélì, Jérémáíà, Hódáfíà àti Jáhídíélì àwọn alágbára akọni ọkùnrin, ọkùnrin olókìkí, àti olórí ilé àwọn baba wọn Wọ́n sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì se àgbérè tọ àwọn ọlọ́run ènìyàn ilẹ̀ náà lẹ́yìn, tí Ọlọ́run ti parun ní iwájú wọn Nítorí náà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ru ẹmi Púlù ọba Ásíríà sókè, ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ó sì kó wọn wá sí Hálà, àti Hábórì, àti Hárà, àti sí ọ̀dọ̀ Gósánì títí dí òní yìí Léfì Àwọn ọmọ Léfì Gérísónì, Kóhátì àti Mérárì Àwọn ọmọ Kóhátì Ámírámù, Ísárì, Hébírónì, àti Húsíélì Àwọn ọmọ Ámírámù Árónì, Mósè àti Míríámù Àwọn ọmọkùnrin Árónì Nádábù, Ábíhù, Élíásérì àti Ítamárì Élíásérì jẹ́ baba Fínéhásì, Fínéhásì baba Ábísúà Ábísúà baba Búkì, Búkì baba Húṣì, Húsì baba Ṣéráhíà, Ṣéráhíà baba Méráíótì, Méráíótì baba Ámáríyà, Ámáríyà baba Áhítúbì Álítúbù bàbá Ṣádókù, Ṣádókù baba Áhímásì, Áhímásì baba Áṣáríyà, Ásáríyà baba Jóhánánì, Jóhánánì baba Áṣáríyà , Áṣáríyà baba Ámáríyà Ámáríyà baba Áhítúbì Áhítúbì baba Ṣádókù Ṣádókù baba Ṣálúmù, Ṣálúmù baba Hílíkíyà, Hílíkíyà baba Áṣáríyà, Áṣáríyà baba Ṣéráíà, pẹ̀lú Ṣéráíà baba Jéhósádákì A kó Jéhósádákì lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Júdà àti Jérúsálẹ́mù kúrò ní ìlú nípaṣẹ̀ Nebukadinésárì Àwọn ọmọ Léfì Gérísónì, kóhátì àti Mérárì Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Géríṣónì Líbínì àti Ṣíméhì Àwọn ọmọ Kéhátì Ámírámù, Íṣárì, Hébírónì àti Húsíélì Àwọn ọmọ Mérárì Máhílì àti Múṣì Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Léfì tí a kọ ní ṣíṣẹ̀ ń tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn Ti Gérísómù Líbínì ọmọkùnrin Rẹ̀, Jéhátì Ọmọkùnrin Rẹ̀, Ṣímà ọmọkùnrin Rẹ̀, Jóáhì ọmọkùnrin Rẹ̀, Idò ọmọkùnrin Rẹ̀, Ṣéráhì ọmọkùnrin Rẹ̀ àti Jéátéráì ọmọkùnrin Rẹ̀ Àwọn ìran ọmọ Kóhátì Ámínádábù ọmọkùnrin Rẹ̀, Kóráhì ọmọkùnrin Rẹ̀, Ásírì ọmọkùnrin Rẹ̀ Élikánà ọmọkùnrin Rẹ̀, Ébíásáfí ọmọkùnrin Rẹ̀, Ásírì ọmọkùnrin Rẹ̀ Táhátì ọmọkùnrin Rẹ̀, Úríélì ọmọkùnrin Rẹ̀, Úsíáhì ọmọkùnrin Rẹ̀ àti Ṣọ́ọ̀lù ọmọkùnrin Rẹ̀ Àwọn ìran ọmọ Élíkánáhì Ámásáyì, Áhímótì Élíkáná ọmọ Rẹ̀, Ṣófáì ọmọ Rẹ̀ Náhátì ọmọ Rẹ̀, Élíábù ọmọ Rẹ̀, Jéríhámù ọmọ Rẹ̀, Élíkáná ọmọ Rẹ̀ àti Ṣámúẹ́lì ọmọ Rẹ̀ Àwọn ọmọ Ṣámúẹ́lì Jóẹ́lì àkọ́bí àti Ábíjà ọmọẹlẹ́ẹ̀kejì Àwọn ìran ọmọ Mérárì Máhílì, Líbínì ọmọ Rẹ̀ Ṣíméhì ọmọ Rẹ̀, Úṣáhì ọmọ Rẹ̀ Ṣíméà, ọmọ Rẹ̀ Hágíáhì ọmọ Rẹ̀ àti Ásáíáhì ọmọ Rẹ̀ Èyí ní àwọn ọkùnrin Dáfídì tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sínmìn níbẹ̀ Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin ńiwájú Àgọ́ ìpàdé títí tí Ṣólómónì fi kọ́ ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù Wọ́n se iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kóhátítè Hémánì olùkọrin, ọmọ Jóẹ́lì, ọmọ Ṣámúẹ́lì, Ọmọ Élíkánáhì ọmọ Jéróhámù, ọmọ Élíéli, ọmọ Tóhà Ọmọ Ṣúfì, ọmọ Élíkáná, ọmọ Máhátì, ọmọ Ámásáyì, Ọmọ Élíkánà, ọmọ Jóẹ́lì, ọmọ Ásárááhì, ọmọ Ṣéfáníáhì Ọmọ Táhátì, ọmọ Áṣírì, ọmọ Ébíásáfì ọmọ Kóráhì, ọmọ Íṣíhárì, ọmọ Kóhátì ọmọ Léfì, ọmọ Ísírẹ́lì Hémánì sì darapọ̀ mọ́ Ásátì, ẹni tí Ó sìn ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ Ásátì ọmọ bérékíáhì, ọmọ Ṣíméà, Ọmọ Míkáélì, ọmọ Bááséíáhì, ọmọ Málíkíjáhì Ọmọ Étínì, ọmọ Ṣéráhì, ọmọ Ádáyà, Ọmọ Étanì, ọmọ Ṣímáhì, ọmọ Ṣíméhì, Ọmọ Jáhátì, ọmọ Gérísíónì, ọmọ Léfì láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Mérárì wà ní ọwọ́ òsì Rẹ̀ Étanì ọmọ Kísì, ọmọ Ábídì, ọmọ Málúkì, Ọmọ Háṣábíáhì ọmọ Ámásáyà, ọmọ Hítíkíáhì, Ọmọ Ámíṣì ọmọ Bánì, ọmọ Ṣémérì, Ọmọ Máhílì, ọmọ Múṣì, ọmọ Mérárì, ọmọ Léfì Àwọn Léfì ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yókù ti Àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run Ṣùgbọ́n Árónì àti àwọn ìran ọmọ Rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ọrẹ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a se ní ibi mímọ́ jùlọ Ṣíṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti paláṣẹ Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Árónì Élíásérì ọmọ Rẹ̀ Fínéhásì ọmọ Rẹ̀, Ábísúà ọmọ Rẹ̀, Búkì ọmọ Rẹ̀, Húṣì ọmọ Rẹ̀ Ṣéráhíà ọmọ Rẹ̀, Méráíótì ọmọ Rẹ̀, Ámáríyà ọmọ Rẹ̀, Áhítúbì ọmọ Rẹ̀, Ṣádókù ọmọ Rẹ̀ àti Áhímásì ọmọ Rẹ̀ Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbégbé wọn A fún wọn ní Hébírónì ní Júdà pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún kelẹ́bù ọmọ Jéfúnénì Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Árónì ni a fún ní Hébírónì , àti Líbínà, Játírì, Éṣitémóà, Hílénì Débírì, Áṣánì, Júlà àti Bétí-Ṣéméṣì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀ Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Béńjámínì, a fún wọn ní Gíbíónì, Gébà, Álémétì àti Ánátótì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrin àwọn ẹ̀yà kóháhítè jẹ́ mẹ́talá ní gbogbo Rẹ̀ Ìyòókù àwọn ìran ọmọ Kóháhítì ní a pín ìlú mẹ́wá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè Àwọn ìran ọmọ Géríṣómù, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Íṣákárì, Áṣérì àti Náfítalì, àti láti apá ẹ̀yà Mánásè tí ó wà ní Básánì Àwọn ìran ọmọ Mérárì, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti Ṣébúlúní Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún àwọn ará Léfì ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn Láti ẹ̀yà Júdà, Síméónì àti Bẹ́ńjámínì ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún Lára àwọn ìdílé Kóhátì ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Éfúráímù gẹ́gẹ́ bí ìlú agbégbé wọn Ní òkè orílẹ̀ èdè Éfíráímù, a fún wọn ní Ṣékémù , àti Géṣérì Jókíméámù, Bétì-Hórónì Áíjálónì àti Gátì Rímónì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún Ádérì àti Bíléámù lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kóhátítè Àwọn ará Géríṣónítè gbà nǹkan wọ̀nyí Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Mánásè wọ́n gba Gólánì ní Básánì àti pẹ̀lú Áṣítarótì, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn Láti ẹ̀yà Ísákárì wọ́n gba Kádéṣì, Dábérátì Rámótì àti Ánénù, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn Láti ẹ̀yà Áṣérì wọ́n gba Máṣálì Ábídónì, Húkokì àti Réhóbù lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Náfítalì wọ́n gba Kédésì ní Gálílì, Hámoníà Kíríátaímù, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn Àwọn ará Mérárì gbà nǹkan wọ̀nyí Láti ẹ̀yà Sébúlúnì wọ́n gba Jókíneámù, Kárítahì, Rímónò àti Tábórì, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn Láti ẹ̀yà Rúbẹ́nì rékọjá Jódánì ìlà oòrùn Jẹ́ríkò wọ́n gba Bésérì nínú ihà Jáhíṣáhì, Kédémótì àti Méfátù, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko, tútù wọn Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gádì wọ́n gba Rámóà ní Gílíádì Máhánáímù, Hésíbónì àti Jáṣérì lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn Ísákárì Àwọn ọmọ Ísákárì Tólà, Púà, Jáṣúbù àti Ṣímírónì, Mẹ́rin ni gbogbo Rẹ̀ Àwọn ọmọ Tólà Húsì, Réfáíáhì, Jéríélì, Jámáì, Jíbísámù àti Ṣámúẹ́lì Olórí àwọn ìdílé wọn Ní àkókò ìjọba, Dáfídì, àwọn ìran ọmọ Tólà tò lẹ́sẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin alágbára ní ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé ẹgbẹ̀ta Àwọn ọmọ, Húṣì Ísíráhíà Àwọn ọmọ Ísíráhíà Míkáélì Ọbádáyà, Jóẹ́lì àti Ísíhíáhì Gbogbo àwọn máràrùn sì jẹ́ olóyè Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n ní ọkùnrin ẹgbàá mérìndínlógójì tí ó ti ṣe tan fún ogun, nítorí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó Àwọn ìbátan tí ó jẹ́ alágbára akọni àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ti àwọn ìdílé Ísákárì, bí a ti tò ó lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlàádórin ni gbogbo Rẹ̀ Àwọn ọmọ mẹ́ta Bẹ́ńjámínì Bélà, Békérì àti Jédíáélì Àwọn ọmọ Bélà Éṣíbónì, Húṣì, Ísíélì, Jérómótì àti Írì, àwọn máràrùnún Awọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbàámọ́kànlá-ó-lé-mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ènìyàn Àwọn ọmọ Békérì Ṣémíráhì, Jóáṣì, Élíásérì, Élíóénáì, omírì, Jeremótù Ábíjà, Ánátótì àti Álémétì Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ọmọ Békérì Ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn tí a kọ lẹ́sẹsẹ jẹ́ ti àwọn olórí ìdílé àti ẹgbẹ̀rún-ní ọ̀nà ogún-ó-lé nígba Ọkùnrin alágbára Ọmọ Jédíáélì Bílíhánì Àwọn ọmọ Bílíhánì Jéúṣì Bẹ́ńjámínì, Éhúdì, Kénánà Ṣétanì, Tárí-Ṣíṣì àti Áhísáhárì Gbogbo àwọn ọmọ Jédíádì jẹ́ olórí ìdátan Àwọn ẹgbẹ̀rúnmẹ́tadínlógún-ó-lé-nígba akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetan láti jáde lọ sí ogun Àwọn ará Ṣúpímè àti Húpímù jẹ́ àwọn atẹ̀lé fún Írì, àwọn ìran ọmọ Áhérì Àwọn ọmọ Náfítalì Jáhíṣíẹ́lì, Gúnì, Jésérì àti Ṣílémù—ọmọ Rẹ̀ nípa Bílíhà Àwọn ìran ọmọ Mánásè Ásíríélì jẹ́ ìran ọmọ Rẹ̀ nípa sẹ̀ àlè Rẹ̀ ará Árámù ó bí Mákírì baba Gílíádì Mákírì sì mú ìyàwó láti àárin àwọn ará Hípímù àti Ṣúpímù Orúkọ arábìnrin Rẹ̀ a má a jẹ́ Máákà Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a má a jẹ́ Ṣélóféhádì, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo Máákà, ìyàwó Mákírì bí ọmọkùnrin kan Ó sì sọ orúkọ Rẹ̀ ní Pérésì Ó sì pe arákùnrin Rẹ̀ ní Ṣéréṣì, àwọn ọmọ Rẹ̀ sì ní Úlámù àti Rákémù Ọmọ Úlámù Bédánì Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gílíádì ọmọ Mákírì, ọmọ Mánásè Arábìnrin Rẹ̀ Hámólékétì bí Ṣíhódì, Ábíésérì àti Máhíláhì Àwọn ọmọ Ṣémídà sì jẹ́ Áhíánì, Ṣékémù, Líkì àti Áníámù Àwọn ìran ọmọ Éfíráímù Ṣútéláhì, Bérédì ọmọkùnrin Rẹ̀, Táhátì ọmọ Rẹ̀, Éléádáhì ọmọ Rẹ̀ Táhátì ọmọ Rẹ̀ Ṣábádì ọmọ, Rẹ̀, àti Ṣútéláhì ọmọ Rẹ̀ Éṣérì àti Éléádì ni a pá nípaṣẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gátì Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn Éfíráímù baba wọn sọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan Rẹ̀ wá láti tù ú nínú Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó Rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan Ó sì sọ ọ́ ní Béríà nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà Ọmọbìnrin Rẹ̀ sì jẹ́ Ṣárà, ẹni tí ó kọ́ ìsàlẹ̀ àti òkè Bétí-Hórónì àti Úṣénì sérà pẹ̀lú Réfà jẹ́ ọmọ Rẹ̀, Rẹ́sẹ́fì ọmọ Rẹ̀, Télà ọmọ Rẹ̀, Táhánì ọmọ Rẹ̀, Ládánì ọmọ Rẹ̀ Ámíhúdì ọmọ Rẹ̀, Élíṣámà ọmọ Rẹ̀, Núnì ọmọ Rẹ̀ àti Jóṣúà ọmọ Rẹ̀ Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Bétélì àti àwọn ìletò tí ó yíká, Náránì lọ sí ìhà ìlà oòrùn, Géṣérì àti àwọn ìletò Rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn àti Ṣékémù àti àwọn ìletò Rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Áyáhì àti àwọn ìletò Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Mánásè ni Bétí ṣánì, Tánákì, Mógídò àti Dórì lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò Rẹ̀ Àwọn ìran ọmọ Jóṣẹ́fù ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí Àwọn ọmọ Ásérì Ímíná, Ísúa, Ísúáì àti Béríá Arábìnrin wọn sì jẹ́ Ṣérà Àwọn ọmọ Béríá Hébérì àti Málíkíélì, tí ó jẹ́ baba Bírísáítì Hébérì jẹ́ baba Jáfílétì, Ṣómérì àti Hótamì àti ti arábìnrin wọn Ṣúà Àwọn ọmọ Jáfílétì Pásákì, Bímíhátì àti Ásífátì Wọ̀n yí ni àwọn ọmọ Jáfílétì Àwọn ọmọ Ṣómérì Áhì, Rógà, Jáhúbà àti Árámù Àwọn ọmọ arákùnrin Rẹ̀ Hélémù Ṣófà, Ímínà, Ṣélésì àti Ámálì Àwọn ọmọ Ṣófáhì Ṣúà, Háníférì, Ṣúálì, Bérì Ímírà Béṣérì Hódì, Ṣámà, Ṣílísà, Ítíránì àti Bérà Àwọn ọmọ Jétérì Jéfúnè Písífà àti Árà Àwọn ọmọ Úlà Árà Háníélì àti Résíà Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ìran ọmọ Áṣérì olórí ìdílé, àwọn okùnrin tí a yàn àwọn ògbóyà jagunjagun àti àwọn adarí tí ó dúró sinsin Iye àwọn ọkùnrin tí ó setan fún ogun, gẹ́gẹ́ bí à ti se kọ ọ́ lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n Ìtàn Ìdílé Láti Ọ̀dọ̀ Baba Ńlá Ti Ṣọ́ọ̀lù Ará Bẹ́ńjámínì Bẹ́ńjámínì jẹ́ bàbá Bélà àkọ́bí Rẹ̀, Áṣíbélì ọmọkùnrin ni ẹ̀ẹ̀kejì, Áhárá ẹ̀ẹ̀kẹ́ta, Nóhà ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Ráfà ẹ̀ẹ̀karùnún Àwọn ọmọ Bélà jẹ́ Ádárì, Gérà, Ábíhúdì, Ábísúà, Námánì, Áhóà, Gérà, Ṣéfúfánì àti Húrámù Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Éhúdì, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Gébà tí a sì lé kúrò lọ sí Mánáhátì Námánì Áhíjà àti Gérà, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Úṣà àti Áhíhúdù A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣáháráímù ní Móábù lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó Rẹ̀ sílẹ̀, Húṣímù àti Báárà Nípaṣẹ̀ ìyàwó Rẹ̀ Hódéṣì ó ní Jóbábù ṣíbíà, Méṣà, Málíkámà, Jéúṣì Ṣákíà àti Mírímà Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Rẹ̀, olórí àwọn ìdílé Nípaṣẹ̀ Húṣímù ó ní Ábítúbù àti Élípálì Àwọn ọmọ Élípálì Ébérì, Míṣámì, Ṣémédù Pẹ̀lú Béríà àti Ṣémà, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Áíjálónì àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gátì kúrò Áhíò, Ṣásákì Jérémílò, Ṣébádíà, Árádì, Édérì Míkáélì Íṣífà àti Jóhà jẹ́ àwọn ọmọ Béríà Ṣébàdíáhì, Mésúlámù Hésékì, Hébérì Íṣíméráì, Íṣílíáhì àti Jóbábì jẹ́ àwọn ọmọ Élípálì Jákímì, Ṣíkírì, Ṣábídì, Élíénáì Ṣílétaì Élíélì, Ádáyà, Béráíáhì àti Ṣímírátì jẹ́ àwọn ọmọ, Ṣíméhì Íṣípánì Ébérì, Élíélì, Ábídónì, Ṣíkírì, Hánánì, Hánáníyà, Élámù, Ánítótíjáhì, Ífédíà Pénúélì jẹ́ àwọn ọmọ Ṣásákì Ṣámíséráì, Ṣéháríà, Átalíà Járéṣíà Élíjà àti Ṣíkírì jẹ́ àwọn ọmọ Jéróhámù Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn ìdílé, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ó lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù Jélíélì, baba a Gíbíónì ń gbé ní Gíbíónì Ìyáwó o Rẹ̀ a má jẹ́ Mákà, Àkọ́bí Rẹ̀ a sì má a jẹ́ Ábídónì wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Ṣúrì, Kíṣì, Báláhì, Nérì, Nádábù, Gédórì Áhíò, Ṣékérì Pẹ̀lú Míkílótì, tí ó jẹ́ bàbá Ṣíméà Wọ́n ń gbé lébá ìbátan wọn ní Jérúsálẹ́mù Mérì jẹ́ baba Kíṣì, Kíṣì baba Ṣọ́ọ̀lù àti Ṣọ́ọ̀lù baba Jónátanì, Málìkíṣúà, Ábínádábù àti Ésíbálì Ọmọ Jónátanì Méríbáì tí ó jẹ́ baba Míkà Àwọn ọmọ Míkà Pítónì, Mélékì, Táréà, àti Áhásì Áhásì jẹ́ bàbá a Jéhóádá, Jéhóádá jẹ́ baba a Álémétì Áṣíméfétì àti Ṣímírì, Ṣímírì sì jẹ́ baba a Móṣà Móṣà jẹ́ baba a Bínéà Ráfà sì jẹ́ ọmọ Rẹ̀, Éléásà ọmọ Rẹ̀ àti Áṣélì ọmọ Rẹ̀ Áṣélì ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn Áṣíríkámù, Bókérù, Íṣímáélì, Ṣéáríà, Ọbádáyà àti Hánánì Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Áṣélì Àwọn ọmọ arákùnrin Rẹ̀ Éṣékì Úlámù àkọ́bí Rẹ̀, Jéúṣì ọmọkùnrin ẹ̀ẹ̀kejì àti Élífélétì ẹ̀ẹ̀kẹ́ta Àwọn ọmọ Úlámù jẹ́ ògboyà jagunjagun tí ó lè gbá orin mú Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọ ọmọkùnrin márùndínlọ́gọ́jọ ní gbogbo Rẹ̀ Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ìran ọmọ Bẹ́ńjámínì Àwọn ènìyàn tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù Gbogbo Ísírẹ́lì ni a kọ lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì Àwọn ènìyàn Júdà ni a kó ní ìgbẹ̀kùn lọ sí Bábílónì nítorí àìsòótọ́ wọn Nísìnsìn yìí, àwọn tí ó kọ́ kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà, àwọn ará Léfì àti àwọn Ìránsẹ́ ilé Olúwa Àwọn tí ó wá láti Júdà láti Bẹ́ńjámínì àti láti Éfíráímù àti Mánásè tí ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù jẹ́ Hútayì ọmọ Ámíhúdì, ọmọ Ómírì, Ọmọ Ímírì, ọmọ Bánì, ìran ọmọ Fárésì ọmọ Júdà Tí ará Ṣílò Ásáíà àkọ́bí àti àwọn ọmọ Rẹ̀ Níti ará Ṣérà Jégúélì Àwọn ènìyàn láti júdà sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá Níti ará Ṣálù ọmọ Mésúlámì, ọmọ Hódáfíà ọmọ Hásénúà Íbínéíà ọmọ Jéróhámù Élà ọmọ Húṣì, ọmọ Míkírì àti Mésúlámù ọmọ Ṣéfátíyà ọmọ Régúélì, ọmọ Íbíníjà Àwọn ènìyàn láti Bẹ́ńjámínì gẹ́gẹ́ bí a ti se kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rùn ún ó dín mẹ́rìnlélógójì, Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé Ní ti àwọn àlùfáà Jédáíà Jéhóíáríbì Jákínì Áṣáríyà ọmọ Hílíkíyà, ọmọ Mésúlámù, ọmọ Ṣádókù, ọmọ Méráíótù, ọmọ Áhítúbì, onísẹ́ tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run Ádáyà ọmọ Jéróhámù, ọmọ Páṣúrì, ọmọ Málíkíjà àti Másáì ọmọ Ádíélì, ọmọ Jáhíṣérà, ọmọ Mésúlámù ọmọ Méṣílémítì, ọmọ Ímérì Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run Níti àwọn ará Léfì Ṣémáíà ọmọ Hásíhúbì, ọmọ Ásíríkámù, ọmọ Háṣábíà ará Mérárì Bákíbákárì, Héréṣì, Gálálì àti Mátaníyà, ọmọ Míkà, ọmọ Ṣíkírì, ọmọ Ásáfù Ọbadíà ọmọ Ṣémáíà, ọmọ Gálálì, ọmọ Jédútúnì àti Bérékíà ọmọ Ásà, ọmọ Élíkánà, Tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Nétófá Àwọn Olùtọ́jú Ẹnu Ọ̀nà Ṣálúmù, Ákúbù, Tálímónì, Áhímánì àti arákùnrin wọn, Ṣálúmì olóyè wọn, ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà oòrùn títí di àkókò yí Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Léfì Ṣálúmì ọmọ kórè ọmọ Ébíásáfì, ọmọ kórà, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ẹlẹ́gbẹ́ Rẹ̀ Láti ìdílé Rẹ̀ ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìlóró ẹnu ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ à bá wọlé ibùgbé Olúwa Ní ìgbà àkọ́kọ́ fíníhásì ọmọ Élíásérì jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà, Olúwa sì wà pẹ̀lú Rẹ̀ Ṣékáríà, ọmọ Méṣélémíà jẹ́ Olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ní à bá wọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé Gbogbo Rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ní àwọn ìlóró ẹnu ọ̀nà jẹ́ ìgba o lé méjìlá A kòmọ̀-ọ́n fún ìràntí nípa ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn ní àwọn ìletò wọn Àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò ìgbàgbọ́ wọn láti ọ̀dọ̀ Dáfídì àti Ṣámúẹ́lì aríran Àwọn àti àtẹ̀lé wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́ Àwọn olùtọ́ju ẹnu ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìlà oòrùn, ìwọ̀ oòrùn àríwá àti gúsù Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín isẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje Ṣùgbọ́n àwọn olórí olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Léfì ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìsúra ní ilé Olúwa Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Olúwa ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ Wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀ Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Olúwa wọn a má a kàá nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí òlóòórìn dídùn Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípo tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀ Ará Léfì tí a sọ ní Mátítíhíà, àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣálúmì ará kórà ni a yàn sí ìdí dídín àkàrà ọrẹ Lára àwọn arákùnrin wọn kora wọn wà ní ìdí ṣísètò fún àkàrà tí a máa ń gbé sórí àga tábìlì ní ọjọjọ́ Ìsinmi Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin, olórí àwọn ìdílé Léfì dúró nínú àgọ́ ilé Olúwa , wọn kò sì se lára isẹ́ ìsìn yòókù nítorí wọ́n ń se isẹ́ náà lọ́sán, lóru Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn Léfì, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti se kọ lẹ́sẹsẹ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù Jélíélì baba Gíbíónì ń gbé ní Gíbíónì Orúkọ ìyàwó Rẹ̀ a má a jẹ́ Mákà, Pẹ̀lú àkọ́bí ọmọkùnrin Rẹ̀ jẹ́ Ábídónì, tí wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Ṣúrì, Kíṣì Bálì, Nérì, Nádábù Gédórì, Áhíò, Sékaráyà àti Míkílótì Míkílótì jẹ́ baba Ṣíméámì, àwọn náà ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jérúsálẹ́mù Nérì jẹ́ baba Kíṣì, Kíṣì baba a Ṣọ́ọ̀lù, àti Ṣọ́ọ̀lù baba a Jónátanì, àti Málíkíṣuà, Ábínádábù àti Éṣí-Bálì Ọmọ Jónátanì Méríbú Bálì, tí ó jẹ́ baba a Míkà Àwọn ọmọ Míkà Pítónì Mélékì, Táhíréà àti Áhásì Áhásì jẹ́ baba Jádà, Jádà jẹ́ baba Álémétì, Aṣimáfétì, Ṣímírì, sì Ṣímírì jẹ́ baba Móṣà Móṣà jẹ́ baba Bínéà Réfáíà jẹ́ ọmọ Rẹ̀, Éléásà ọmọ Rẹ̀ àti Áṣélì ọmọ Rẹ̀ Áṣélì ní ọmọ mẹ́fà, pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn Áṣíríkámù, Bókérù, Ísímáélì Ṣéáríà, Óbádíà àti Hánánì Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Áṣélì Ìdúpẹ́ Pọ́ọ̀lù, ẹni ti a pé láti jẹ́ àpósítélì Kírísítì Jésù nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Sósíténì arákùnrin wa Sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run ni Kọ́ríńtì, sí àwọn ti a sọ di mímọ́ nínú Jésù Kírísítì àti àwọn ti a pè láti jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ni ibikíbi ti ń pe orúkọ Olúwa wa Jésù Kírísítì ẹni ti ń ṣe Olúwa tiwọn àti ti àwa náà Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jésù Kírísítì Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kírísítì Jésù Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kírísítì ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyì ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jésù Kírísítì Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì Ọlọ́run, nípaṣẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa, jẹ́ Olótítọ́ Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kírísítì, pé kí gbogbo yín fohùnsọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyàpá láàrin yín, àtipé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kiloe sọ di mímọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrin yín Ohun tí mo ń sọ ni pé Olúkúlùku yín ń wí pé, Èmí tẹ̀lé Pọ́ọ̀lù Èmi tẹ̀lé Àpólò òm̀íràn, Èmi tẹ̀lé Kéfà, ìtúmọ̀, Pétérù àti ẹlòmìíràn, Èmi tẹ̀lé Kírísítì Ǹjẹ́ a há pín Jésù bí Ṣé a kan Pọ́ọ̀lù mọ́ àgbélébùú fún un yín bí Ǹjẹ́ a tẹ̀yín bọmi yín ní orúkọ Pọ́ọ̀lù bí Inú mi dún púpọ̀ pé èmi kò tẹ ẹnikẹ́ni nínú yín bọmi yàtọ̀ sí Kírísípù àti Gáíù Nítorí náà kò sí ẹni tí ó lè sọ pé òun ṣe ìtẹ̀bọmi ní orúkọ èmi fúnraara mi Nítorí Kírísítì kò rán mi láti máa ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n Ó rán mi láti máa wàásù ìyìn rere kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn, kí a máa ṣe sọ àgbélébú Kírísítì dí aláìlágbára Nítorí pé òmùgọ̀ ni ọ̀rọ̀ àgbélébùú jẹ́ sí àwọn tí ń sègbé, ṣùgbọ́n fún àwa tí a ń gbàlà ó jẹ́ agbára Ọlọ́run Nítorí tí kọ ọ́ pé Èmi yóò pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run, òye àwọn olóye ni Èmi yóò sọ di asán Àwọn ọlọ́gbọ́n ha dá Àwọn ọ̀mọ̀wé ha dà Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ayé yìí ha dà Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di òmùgọ̀ Nítorí pé, nínú ọgbọ́n Ọlọ́run, ayé kò le mọ̀ òun nípa ọgbọ́n àti ìṣeféfé wọn Ó sì gba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa ìwàásù tí àwọn aráyé pè ní òmùgọ̀ àti ọ̀rọ̀ ọ yẹ̀yẹ́ Nítorí pé àwọn Júù ń bèrè àmì, àwọn Gíríkì sí ń ṣàfẹ́rí ọgbọ́n ṣùgbọ́n àwọn ń wàásù Kírísítì ti a kàn mọ́ àgbélébùú, òkúta ìkọ̀sẹ̀ àwọn Júù àti òmùgọ̀ fún àwọn kèfèrí ṣùgbọ́n sí àwọn tí Ọlọ́run tí pè, àti àwọn Júù àti àwọn Gíríkì, Kírísítì ni agbára Ọlọ́run, àti ọgbọ́n Ọlọ́run Nítorí pé òmùgọ̀ Ọlọ́run jù ọgbọ́n ènìyàn lọ àti aláìlera Ọlọ́run ni agbára jù ìlera ènìyàn lọ Ará, ẹ kíyèsí ohun tí nígbà tí a pè yín Bí ó ti ṣe pé, kì í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn nípa ti ara, kí í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà, kì ì ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́lá ni a pè Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí yàn àwọn òmùgọ̀ ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n Ọlọ́run sì ti yàn àwọn ohun aláìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ni agbára Ó ti yan ètò tí ayé kẹ́gàn, tí wọn kò kà sí rárá, láti sọ nǹkan tí wọ́n kà sí ńlá di ohun asán àti aláìwúlò Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀ Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kírísítì Jésù ẹni ti ó já sí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyi ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa Nítorí náà, bí a ti kọ ọ́ pé, Ẹni ti ó bá ń ṣògo kí ó máa ṣògo nínú Olúwa Ìkìlọ Láti Inú Ìtàn Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Nítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè si òtítọ́, ẹ̀yin arakùnrin ọ̀wọ́n, a kó gbọdọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wa nínú ihà Ọlọ́run samọ̀nà wọn nípa rírán ìkùúkù ṣíwájú wọn, ó sì sìn wọ́n la omi òkun pupa já A lè pe eléyìí ní ìtèbọmi sí Mósè nínú ìkùúkù àti nínú omi òkun Nípa iṣẹ́ ìyanu, gbogbo wọn jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà Wọ́n mu nínú omi tí Kírísítì fi fún wọn Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kírísítì Ó wà pẹ̀lú wọn nínú ihà náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ lẹ́yin èyí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni kò ṣe ìgbọ́ràn sí Ọlọ́run Òun sì pa wọ́n run nínú ihà Ẹ̀kọ́ tí a lè kọ́ yìí jásí àpẹrẹ fún wa, kí a má ṣe ní ìfẹ̀ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn nínú ihà Kí ẹyin má ṣe sin ère òrìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti jó Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbérè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbàá-mọ̀kànlá-lé-ẹgbẹ̀rún ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n Gbogbo àwọn nǹkan tí mo ń wí wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n sì jẹ́ àpẹrẹ, fún wa, wọ́n kọ wọ́n sílẹ̀ bí ikìlọ̀ fún wa láti yàgò kúrò nínú síṣe àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ A kọ èyí sílẹ̀ fún kíkà wa ní àkókò yìí tí aye fi ń lọ sópin Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à subú Kò sí ìdànwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó ti bá ènìyàn rí, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlórun, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ̀n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ́yin baà lè faradà á Nítorí náà, ẹ̀yín olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà Èmi ń sọ̀rọ̀ sí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ṣe ìdájọ́ fúnra rẹ̀ ohun tí mo sọ Ago ìbùkún tí a ń súre sí, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábàápín ìdàpọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ Kírísítì bí Àkàrà tí a bù, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábàápín nínú ara Kírísítì bi Bí ó ti wù kí ènìyàn pọ̀ níbẹ́ tó, gbogbo wa ní ń jẹ lára àkàrà ẹyọkan ṣoṣo náà Eléyìí fi hàn wá pé gbogbo wá jẹ́ ẹ̀yà ara kan Ẹ wo Ísírẹ́lì nípa ti ara, àwọn tí ń jẹ ohun ẹbọ kò ha se alábàápín pẹpẹ bí Ǹjẹ́ kí ni mo ń wí Ṣé pé ohun tí a fi rubọ sí òrìsà jẹ́ nǹkan kan tàbí pé òrìsà jẹ́ nǹkan kan Rárá, ṣùgbọ́n ohun tí mo ń wí ni pé, ohun tí àwọn aláìkọlà fi ń rúbọ wọn sí àwọn ẹ̀mí èsù Dájúdájú kì í ṣe ìrúbọ sí Ọlọ́run Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí èṣù Ẹ̀yin kò lè mu nínú kọ́ọ́bù tí Olúwa àti kọ̀ọ́bù ti èṣù lẹ̀ẹ́kan náà Ẹ kò lè jẹun ní tábìlì Olúwa kí ẹ tún jẹ tábìlì ẹ̀mí èsù lẹ́ẹ̀kan náà Kí ni ẹ̀ ń gbìyànjú láti ṣe Àwa ha ń mú Olúwa jowú bí Àwa ha ní agbára jù ú lọ Ohun gbogbo ni o yẹ fún mi, ṣùgbọ̀n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ń gbe ni rò Má ṣe ronú nípa ara rẹ̀ nǹkan ṣùgbọ́n kí olúkúkù máa wá ire ọmọnikéji rẹ̀ Jẹ ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá ń tà lọ́jà Má ṣe gbìyànjú láti wádìí lọ́wọ́ ẹni tí ń tà á nítorí ẹ̀rí ọkàn Nítorí Ayé àti gbogbo nǹkan rere tí ń bẹ nínú rẹ̀, tí Olúwa ni wọ́n jẹ́ Bí ẹnìkẹ̀ni tí kì í bá ṣe onígbàgbọ́ ba pè yín sí ibi àṣè láti jẹun, bá a lọ Gba ìpè rẹ̀ tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rún Jẹ ohunkóhun tí ó bá pèsè sílẹ̀ fún àṣè náà, má ṣe béèrè ohunkóhun nípa rẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn Bí ẹnikẹ́nì bá sì kìlọ̀ fún un yín pé a ti fi ẹran yìí rúbọ sí òriṣà, má ṣe jẹ́ ẹ nítorí ẹ̀rí ọkàn tí ó kìlọ̀ fún ọ́ pé a ti fi rúbọ sí òrìṣà Nǹkan tí ó ṣe pàtàkì ní irú ipò yìí ni ẹ̀rí ọkàn àti èrò ọkùnrin náà, nítorí kì í ṣe ẹ̀rí ọkàn ẹlòmìíràn ní a ó fi dá òmìnira mi lẹ́jọ́ Bí èmi ba fi ọpẹ́ jẹ ẹ́, è é ṣe tí a fì ń sọ̀rọ̀ mi ní búbúrú nítorí ohun tí èmi dúpẹ́ fún Nítorí náà tí ẹ̀yin bá jẹ tàbí tí ẹ bá mu tàbí ohunkohun tí ẹ̀yin bá sè, e máa ṣe gbogbo rẹ̀ fún ògo Ọlọ́run Nítorí náà, má ṣe jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ ìbá à ṣe Júù tàbí Gíríkì tàbí ìjọ Ọlọ́run rẹ̀ Bí ṣè n gbìyanjú láti tẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́rùn nínú gbogbo nǹkan tí mo bá ń ṣe láì wa ohun rere fún ara mi bí kò ṣe ti ènìyàn púpọ̀ kí ó lè ṣe é ṣe fún wọn láti le ní ìgbàlà Ìbámu Nínú Ìsìn Ẹ máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ mi, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ Kírísítì Èmí yìn yín fún rírántí mi nínú ohun gbogbo àti fún didi gbogbo ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ yín mú sinsin gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi lélẹ̀ fún un yín Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ̀yin mọ̀ pé, Kírísítì ni orí olukúlúkù ọkùnrin, orí obìnrin sì ni ọkọ rẹ̀ àti orí Kírísítì sì ní Ọlọ́run Gbogbo ọkùnrin tó bá borí rẹ̀ nígbà tó bá ń gbàdúrà tàbí sọtẹ́lẹ̀ kò bọ̀wọ̀ fún orí rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ náà ni obìnrin tí ó bá ń gbàdúrà tàbí tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ láìbo orí rẹ̀, kò bu ọlá fún orí ara rẹ̀ nítorí ọ̀kan náà ni pẹ̀lú ẹni tí ó fárí Ṣùgbọ́n tí obìnrin bá kọ̀ láti bo orí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó gé irun rẹ̀ Bí ó bá sì jẹ́ nǹkan ìtìjú fún un làti gé irun orí rẹ́, nígbà náà kí ó fi gèlè bo orí rẹ̀ Ṣugbọ́n ọkùnrin kò ní láti fi nǹkan bo orí rẹ́ nígbà tí ó bá ń sìn, nítorí àwọrán àti ògo Ọlọ́run ni òun í ṣe, ṣùgbọ́n ògo ọkùnrin ni obìnrin í ṣe Ọkùnrin kò ti inú obìnrin wá, ṣùgbọ́n a yọ obìnrin jáde lára ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni a kò dá ọkùnrin fún àǹfààní obìnrin ṣùgbọ́n a da obìnrin fún ọkùnrin Nítorí ìdí èyí àti nítorí àwọn ańgẹ́lì, ni obìnrin ṣe gbọdọ̀ ní àmì àṣẹ rẹ̀ ní orí rẹ̀ Ẹ rántí pé, nínú ètò Ọlọ́run obìnrin kò lè wà láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin kò lè wà láàsí obìnrin Lóòtọ́ láti ara ọkùnrin ni a ti yọ obìnrin jáde bẹ́ẹ̀ si ni ọkùnrin tipàsẹ obìnrin wa Ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ohun gbogbo ti wà Kí ni ẹ̀yìn fún ra yín rò lórí ọ̀rọ̀ yìí Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún obìnrin láti máa gbàdúrà ní gbangba láìbo orí rẹ̀ bí Njẹ́ ìwà abínibí yín kò ha kọ́ yín pé, bí ọkùnrin bá ní irun gígùn, àbùkù ni ó jẹ́ fún un Ṣùgbọ́n bí obìnrin bá ní irun gígún, ògo ni ó jẹ́ fùn un nítorí irun gígùn tí a fi fún un jẹ́ ìbòrí fún-ún Ṣùgbọ́n tí ẹnìkẹ́ni bá fẹ́ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, ohun kan tí mo lè sọ sí gbogbo rẹ̀ ni pé, a kò ní àṣà tí ó yàtọ̀ sí èyí tí mo ti sọ, pé obìnrin gbọdọ̀ fi gèlè bo orí rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ tàbí tí ó bá ń gbàdúrà láàrin ìjọ Ọlọ́run Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá pé jọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú Lọ́nà kínní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrin yín ní ìgbà tí ẹ bá pé jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan Kò sí àníàní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrin yín, kí àwọn tí ó yanjú láàrin yín le farahàn kedere Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olukúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkèjì rẹ̀ Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní Kí ni kí èmi ó wí fún un yín Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí A! Rárá o Èmi kọ́, n kò ní yìn yín Nítorí èyí tí èmi gbà lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti fi fún un yin Ní alẹ́ ọjọ́ tí Júdásì fi hàn, Olúwa Jésù Kírísítì mú búrẹ́dí Lẹ́yìn igbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi Bákan náà ló mu kọ́ọ̀bù ọtí wáìnì lẹ́yìn oúnjẹ, ó sì wí pé, Kọ́ọ̀bù yìí ní májẹ̀mú titun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi Nítorí nígbákùúgbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú kọ́ọ̀bù yìí, ni ẹ tún sọ nipa ikú Olúwa Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú kọ́ọ̀bù Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáadáa kí ó tó jẹ lára àkàrà nàá àti kí ó tó mu nínú ife náà Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú kọ́ọ̀bù láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kírísítì áti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń sàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn Ṣùgbọ́n tí ẹ bá yẹ ara yín wò dáadáa, kí ẹ tó jẹ ẹ́, a kì yóò dá yín lẹ́jọ́ Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ti Olúwa bá tilẹ̀ ṣe ìdájọ́ wa, tí ó sì jẹ wá níyà nítorí àwọn àṣìṣe wa, ó dára bẹ́ẹ̀, ó ń ṣe bẹ́ẹ̀, kí a má baà dá wa lẹ́jọ́, kí a sì pa wá run pẹ̀lú ayé Nítorí náà, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, nígbàkúùgbà ti ẹ bá péjọ láti jẹ́ oúnjẹ alẹ́ Olúwa, tàbi fún ìsìn oúnjẹ alẹ́ Olúwa, ẹ dúró de ara yín Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni nínú yin, kí ó jẹun láti ilé wá, kí ó má baá mú ìjìyà wá sórí ara rẹ̀ nígbà tí ẹ bá pé jọ Tí mo bá dé, èmi yóò máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ ìyókù tí n kò ì ti fẹnu bà lẹ́sẹsẹ Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ Ní ti Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin ará, kò yẹ́ kí ẹ jẹ́ òpè Ẹ̀yin kò mọ̀ pé nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ abọ̀rìṣà, a fà yín lọ sọ́dọ̀ odi òrìṣà, ni ọ̀nà tí ó wù kí a gbà fà yín lọ Nítorí náà, èmí ń sọ fún un yín pé kò sí ẹni ti ń sọ̀rọ̀ nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó lè wí pé, Ẹni ìfibú ni Jésù, àti pé kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, Olúwa ni Jésù, bí kò ṣe nípàṣẹ̀ Ẹ̀mí mímọ́ Ǹjẹ́ onírúurú ẹ̀bùn ni ó wà, ùgbọ́n Ẹ̀mí kan náà ni Onírúurú iṣẹ́-ìranṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà sì ni Onírúurú iṣẹ́-ìranṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n lọ́run kan náà ni ẹni tí ń ṣisẹ́ gbogbo wọn níní gbogbo wọn Ṣùgbọ́n à ń fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fún olúkúlùkù ènìyàn láti fi jèrè Ẹ̀mí Mímọ́ lè fún ẹnìkan ní ọgbọ́n láti lè fún ènìyàn lámọ́ràn, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ ńlá Láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mimọ́ kan náà ni èyì ti wá Ó fi ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ fún ẹlòmíràn, ẹlòmíràn ló sì fi agbára ìwonisàn fún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà Ó fi agbára fún àwọn mìíràn láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu Ó fún àwọn mìíràn lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àti láti wàásù pẹ̀lú ìmísí Bákan náà ló fún àwọn kan lẹ́bùn láti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn Ẹ̀mí Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àti agbára láti lè sọ èdè tí wọn kò mọ̀ tí wọn kò rí Bákan náà ó fún àwọn ẹlòmíràn lágbára láti mọ̀ àti láti túmọ̀ èdè tí wọn kò gbọ́ rí Àní, Ẹ̀mi kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan Ara jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan soso Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kírísítì tí í ṣe ìjọ Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitísì gbogbo wa sínú ara kan, ìbáà ṣe Júù, ìbaà ṣe Gíríkì, ìbáà ṣe ẹrú, ìbaà ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀ Tí ẹ̀ṣẹ̀ bá wí pé, Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara, èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara Bí etí bá wí pé, Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apákan ara, èyí kò lènu máa jẹ́ apákan ara mọ́ Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú Níbo ni a ó ti ma gbọ́ràn Tí gbogbo ara bá jẹ̀ etí ńkọ́ Ọ̀nà wo la lè gbà gbọ́ òórùn Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà Bí gbogbo wọn bá sì jẹ́ ìkanṣoṣo nínú ẹ̀yà-ara, níbo ni ara yóò gbé wà Ọlọ́run dá ẹ̀yà ara púpọ̀, ṣùgbọ́n ara kan ṣoṣo ni Bí ó tí rí yìí, ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, Èmi kò nílò rẹ Bẹ́ẹ̀ ni orí kò le sọ fún ẹsẹ̀ pé, Èmi kò nílò rẹ Àwọn ẹ̀yà ara tí ó dàbí ẹni pé wọ́n ṣe aláìlágbára jùlọ, tí ó dàbí ẹni pé kò ṣe pàtàkì rárá, àwọn gan-an ni a ko le ṣe aláìnílò Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara ti a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ Àwọn ẹ̀yà ara ti a rò pé yẹ rára ni àwa ń fi ipò ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ sọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀ Gbogbo yín jẹ́ ara Kírísítì, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara Kírísítì Àti nínú ìjọ, Olọ́run ti yan àwọn àpósítélì àkọ́kọ́, èkéjì àwọn wòlíì, ẹni ẹ̀kẹta àwọn Olùkọ́, lẹ́yìn náà, àwọn tí ó ní òsìsẹ́ iṣẹ́ ìyanu, lẹ́yin náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmuláradá, àwọn Olùrànlọ́wọ́ àwọn alákòóso àwọn tí ń sọ onírúurú èdè Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ àpósítélì bi Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí Rárá Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Olọ́run fún lẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ̀n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí Ṣùgbọ́n, ẹ máa fi ìtara sàfẹ́rí ẹ̀bùn ti ó tóbi jù Ṣíbẹ̀ èmi o fi ọ̀nà kan tí ó tayọ rékọjá hàn yín Ìfẹ́ Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti ańgẹ́lì, tí n kò bá sì ní ìfẹ́, mo kàn ń pariwo bí agogo lásàn ni tàbí bí i Síḿbálì olóhùn gooro Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ́, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè sí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ̀, kò ní èrè kan fún mi Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ̀ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga Ìfẹ́ kì í huwa àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìsòótọ́ Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo sí òtítọ́ A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbógbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo Ìfẹ̀ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bún ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán Nítorí àwa mọ̀ ní apá kan, àwa sì sọ tẹ̀lẹ́ ní apá kan Ṣùgbọ́n nígbà tí èyí ti o pé bá dé, èyí tí í ṣe tí apákan yóò dópin Nígbà tí mó wà ni èwe, èmi á máa sọ̀rọ̀ bi èwe, èmi a máa mòye bí èwe, emí a máa gbèrò bí èwe Ṣùgbọ́n nígbà tí mó di ọkùnrin tán, mo fi ìwà èwe sílẹ̀ Nítorí pé nísinsìnyìí àwa ń ríran bàìbàì nínú àwòjìjì nígbà náà a ó rí í lójúkojú Nísinsinyìí mò mọ̀ pé ní apá kan nígbà náà èmi o mọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́, kódà bí mo ti dí mímọ̀ pẹ̀lú Ǹjẹ́ nísinsìnyìí àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí dúró ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ Ṣùgbọ́n èyí tí o tóbi jù nínú wọn ni ìfẹ́ Ẹ̀bùn Ìsọtẹ́lẹ̀ Àti Ìfèdèfọ̀ Ẹ máa lépa ìfẹ́, ki ẹ sí máa fí itará ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, ṣùgbọ́n ki ẹ kúkú lé máa ṣọ tẹ́lẹ̀ Nítorí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, kò bá ènìyàn sọ̀rọ̀ bì ko ṣe Ọlọ́run nítorí kó sí ẹni tí ó gbọ́ ṣùgbọ́n nípá ti Ẹ̀mí ó ń sọ ohun ìjìnlẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ ń ba àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ìmúdúró, àti ìgbani-níyànjú, àti ìtùnú Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹṣẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹṣẹ̀ ìjọ múlẹ̀ Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa, pẹ̀lúpẹ̀lú láti lè máa sọtẹ́lẹ̀ Ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ tóbi jú ẹni ti ń sọ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtúmọ̀, kí ijọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́ Ǹjẹ nísinsìnyìí, ará, bí mo bá wá sí àárin yín, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, èrè kín ni èmí óò jẹ́ fún yin, bi ko ṣe pé mo bá ń bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípa ìṣípayá, tàbí ìmọ̀ tàbí nípá iṣọtẹ́lẹ̀, tàbí nipá ẹ̀kọ́ Bẹ́ẹ̀ ní pẹ̀lú àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí ń dún, ìba à ṣe fèrè tàbí dùùrù bí kò ṣe pé ìyàtọ̀ bá wà nínú wọn, a ó tí ṣe mọ ohùn tí fèrè tàbí tí dùùrù ń wí Nítorí pé bi ohùn ìpè kò bá dájú, ta ni yóò múra fún ogun Bẹ́ẹ̀ sí ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹyin bá ń fí ahọ́n yín sọ̀rọ̀ tí ó yé ni, a ó ti ṣe mọ ohun ti ẹ ń wí Nítorí pé ẹ̀yin yóò kàn máa sọ̀rọ̀ si afẹ́fẹ́ lásán Ó lé jẹ́ pé onírúurú ohùn èdè ní ń bẹ ní ayé, kò sí ọ̀kan tí kò ní ìtumọ̀ Ǹjẹ́ bí èmí kò mọ itúmọ̀ ohùn èdè náà, èmí ó já sí aláìgbédè sí ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ yóò sí já sí aláìgbédè sí mi Bẹ́ẹ̀ si ní ẹ̀yín, bí ẹ̀yín ti ni itara fún ẹ̀bùn Ẹ̀mí, ẹ máa ṣe àfẹ́rí àti máa pọ̀ síi fún ìdàgbàsókè ìjọ Nítorí náà jẹ́ ki ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ gbàdúrà ki ó lè máa ṣe ìtumọ̀ ohun tí ó sọ Nítorí bí èmí bá ń gbàdúrà ní èdè àìmọ̀, ẹ̀mí mi ni ń gbàdúrà, ṣùgbọ́n ọkan mi jẹ́ aláìléso Ǹjẹ́ kín ni èmi ó ṣe Èmí o fí ẹ̀mí mí gbàdúrà, èmi ó sí fí ọkàn gbàdúrà pẹ̀lú Èmi ó fi ẹ̀mí kọrin, èmi o sí fi ọkàn kọrin pẹ̀lú Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ìwọ bá sú ìre nípa ẹ̀mí, báwo ni ẹni tí ń bẹ ni ipò òpè yóò ṣe ṣe Àmín si ìdúpẹ rẹ, nígbà tí kò mọ ohun tí ìwọ́ wí Nítorí ìwọ dúpẹ́ gidigidi nítóótọ́, ṣùgbọ́n a kó fí ẹsẹ̀ ẹnikéjì rẹ múlẹ̀ Mó dúpẹ́ lọwọ Ọlọ́run tí èmi ń fọ̀ onírúurú èdè ju gbogbo yín lọ Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí n kúkú fí ọkàn mi sọ ọ̀rọ̀ márùn-ún ni inú ìjọ, kí n lè kọ́ àwọn ẹ̀lomíran ju ẹgbáarún ọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà A tí kọ ọ́ nínú òfin pé, Nípa àwọn aláhọ́n mìíràn àti elété mìíràn ní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀ síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi, ni Olúwa wí Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí àmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́ ṣùgbọ́n isọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́ Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fí èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ̀kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹyin ń ṣe òmùgọ̀ Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbi tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi aṣiri ọkan rẹ̀ hàn bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sín Ọlọ́run yóò sì sọ pé, Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrin yín! Ǹjẹ́ è é ha ti ṣe, ki ni ki àwa yóò sọ ẹ̀yin ará Nígbà tí ẹ̀yin pé jọ pọ̀, tí olúkúlùkù yín ni Sáàmù kan tàbí ẹ̀kọ́ kan, èdè kan, ìfihàn kan, ìtumọ̀ kan Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láti gbé ìjọ ró Bí ẹnìkan bá fi èdè fọ̀, kí ó jẹ ènìyàn méjì, tàbi bí ó pọ̀ tán, kí ó jẹ́ mẹ́ta, kí ó sọ̀rọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí ẹnìkan sì túmọ̀ rẹ̀, Ṣùgbọ́n bí kò bá sí ògbufọ̀, kí ó pá ẹnu rẹ̀ mọ́ nínú ìjọ sì jẹ́ kí ó máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀ Jẹ́ kí àwọn wòlíì méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, ki àwọn ìyókù sì wòye ìtumọ̀ ohun tí a sọ Bí a bá sì fí ohunkóhun hàn ẹni tí ó jókòó níbẹ̀, jẹ́ kí ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ ṣáájú dákẹ́ Nítorí gbogbo yín lè sọtẹ́lẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọ́kan, kí gbogbo yín lè kọ́ ẹ̀kọ́, kí a lè tu gbogbo yín nínú Ẹ̀mí àwọn wòlíì a sí máa tẹríba fún àwọn wòlíì Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ijọ ènìyàn mímọ́ Jẹ́ ki àwọn obìnrin yín dákẹ́ nínú ijọ nítorí a kò fí fún wọn láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ ki wọn wà lábẹ́ itẹríbá, bí ó ṣe rí ni gbogbo àpéjọ àwọn ènìyàn mímọ́ Bí wọ́n bá sì fẹ́ mọ̀ nípa ohunkóhun, kí wọn bèèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn ní ilé nítorí ohun ìtìjú ni fún àwọn obìnrin láti máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ Kí ni Ṣe lọ́dọ̀ yín ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde ni, tabi ẹ̀yin nìkan ni o tọ̀ wá Bí ẹnikẹ́ni bá ró ará rẹ̀ pé òun jẹ́ wòlíì, tabí òun jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, jẹ́ kí nǹkán wọ̀nyí ti mo kọ sí yin yé e dájú pé ofin Olúwa ni wọ́n Ṣùgbọ́n bí ẹnikan bá fi ojú fo èyí dá, òun fún ra rẹ̀ ní a ó fi ojú fò dá Nítorí náà ará, ẹ máa fí ìtara ṣáfẹrí láti sọtẹ́lẹ̀, kí ẹ má sì ṣe dànílẹ́kún láti fi èdè fọ̀ Ẹ máa ṣe ohun gbogbo tẹ̀yẹtẹ̀yẹ àti lẹ́sẹẹsẹ Àjíǹde Kírísítì Ǹjẹ́ ará, èmi ń sọ ìyinrere náà dí mímọ̀ fún un yín, tí mo ti wàásù fún un yín, èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ti gbá, nínú èyí tí ẹ̀yin sì dúró Nípaṣẹ̀ ìyìn rere yìí ni a fi ń gbà yín là pẹ̀lú, bí ẹ̀yin bá di ọ̀rọ̀ ti mo ti wàásù fún yín mú ṣinṣin Bí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ẹyin kàn gbàgbọ́ lásán Nítorí èyí tí mo rí gbà ṣáájú ohun gbogbo ní èmi pẹ̀lú ti gbà lé e yín lọ́wọ́, bí Kírísítì ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ tí wí Àti pé a sìnkú rẹ̀, àti pé ó jíǹdé ní ijọ́ kẹtà gẹ́gẹ́ bí iwe mímọ́ tí wí Àti pé ó farahàn Pétérù, lẹ́yìn èyí, àwọn méjìlá Lẹ́yìn èyí, ó farahàn àwọn ará tí o jú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tà lọ lẹ́ẹ̀kan náà ọ̀pọ̀ nínú wọn wà títí fí di ìsinsìnyìí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn Lẹ́yìn èyí ni ó farahan Jèmísì lẹ́yìn náà fún gbogbo àwọn Àpósítélì Àti níkẹyín gbogbo wọn ó fáráhàn mí pẹ̀lú, bí ẹni tí a bí ṣáájú àkókò rẹ̀ Nítorí èmi ni ẹni tí ó kéré jùlọ nínú àwọn àpósítélì, èmi ẹni tí kò yẹ láti pè ní àpósítélì, nítorí tí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run Ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run mo rí bí mo ti rí oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí a fí fún mi kò sì jẹ́ asán ṣùgbọ́n mó ṣiṣẹ́ lọ̀pọ̀lọpọ̀ jú gbogbo wọn lọ ṣùgbọ́n kì í ṣe èmi, bí kò ṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó wà pẹ̀lú mi Nítorí náà ìbáà ṣe èmí tabí àwọn ni, bẹ́ẹ̀ ní àwa wàásù, bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀yin sì gbàgbọ́ Ǹjẹ́ bí a bá wàásù Kírísítì pé ó tí jíǹdé kúró nínú òkú, è é há tí ṣe tí àwọn mìíràn nínú yín ti wí pé, àjíǹde òkú kò sí Ṣùgbọ́n bí àjíǹde òkú kò sí, ǹjẹ́ Kírísítì kò jíǹde Bí Kírísítì kò bá sì jíǹde, ǹjẹ́ asán ni ìwàásù wà, asán sì ni ìgbàgbọ́ yín pẹ̀lú Ṣùgbọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ, a mú wa ni ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọ́run nítorí ti àwa jẹ́rìí Ọlọ́run pé ó jí Kírísítì dìdé kúrò nínú òkú ẹni tí òun kò jí dìde bí ó bá ṣe pé àwọn òkú kò jíǹde Nítorí pé bi á kò bá jí àwọn òkú dìde, ǹjẹ́ a kò jí Kírísítì dìdé, Bí a kò bá sì jí Kírísítì dìdé, asán ní ìgbàgbọ́ yín ẹ̀yín wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín síbẹ̀ Ǹjẹ́ àwọn pẹ̀lú tí ó sùn nínú Kírísítì ṣègbé Bí ó bá ṣe pé kìkì ayé yìí nìkan ní àwa ní ìrétí nínú Kírísítì, àwa jásí òtòsì jùlọ nínú gbogbo ènìyàn Ǹjẹ́ nísinsìnyìí Kírísítì tí jíǹde kúró nínú òkú, ó sì dí àkọ́bí nínú àwọn tí ó sùn Nítorí ìgbà tí ó jẹ́ pé nípa ènìyàn ní ikú ti wá, nipá ènìyàn ní àjíǹde òkú sì ti wá pẹ̀lú Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ ní a ó sì sọ gbogbo ènìyàn dí alààyè nínú Kírísitì Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn ní ipá tirẹ̀ Kírísítì àkọ́bí lẹ́yin èyí àwọn tí ó jẹ́ tí Kírísítì ni wíwá rẹ̀ Nígbá náà ni òpín yóò dé, nígbà tí ó bá ti fi ìjọba fún Ọlọ́run Baba, nígbà tí ó bá pá gbogbo àṣẹ àti gbogbo ọlá àti agbára run Nítorí ti òun gbọdọ̀ ti jọba kí òun to fí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí abẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ Ikú ní ọ̀ta ìkẹ́yìn tí a ó párun Nítorí ó ti fí ohun gbogbo sábẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wí pé, Ohun gbogbo ni á fí sí abẹ́ rẹ̀, o dájú pé Ọlọ́run nìkanṣoṣo ní kò sí ní abẹ́ rẹ̀, Òun ní ó fí ohun gbogbo sí abẹ́ àkóso Kírísítì Nígbà tí a bá sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni á ó fi ọmọ tìkárarẹ̀ pẹ̀lú sábẹ́ Ẹni tí ó fí ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jásí ohun gbogbo nínú ohun gbogbo Ní báyìí, bí kò bá sí àjíǹde, kín ní ète àwọn ènìyàn tí wọn ń tẹ bọmi nítorí òkú Bí àwọn òkú kò bá jíǹde rárá, nítorí kín ni a ṣe ń bamítíìsì wọn nítorí wọn Nítorí kínní àwa sì ṣe ń bẹ nínú ewu ni wákàtí gbogbo Mo sọ nípa ayọ̀ tí mo ní lórí yín nínú Kírísítì Jésù Olúwa wá pé, èmi ń kú lojoojúmọ Kí a wí bí ènìyàn, bí mo bá ẹranko jà ní Éfésù, àǹfàání kín ni ó jẹ́ fún mi Bí àwọn òkú kò bá jínde, Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ kí á máa mú nítorí ní ọlá ni àwa ó kú Kí a má tàn yín jẹ́ Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́! Ẹ ji ìjí òdodo, kí ẹ má sì dẹ́ṣẹ̀ nítorí àwọn ẹlómírán kò ni imọ̀ Ọlọ́run mo sọ èyí kí ojú baà lè ti yín Ṣùgbọ́n ẹnìkan yóò wí pé, Báwo ni àwọn òkú yóò ṣe jíǹde Irú ara wó ni wọn ó padà sí Iwọ aláìmòye, ohun tí ìwọ fúnrúgbìn kì í yè bí kò ṣe pé ó kú Àti èyí tí ìwọ fúnrúgbìn, kì í ṣe ara tí ń bọ̀ ni ìwọ fúnrúgbìn, ṣùgbọ́n irúgbín lásán ni, ìbáàṣe àlìkámà, tabi irú mìíràn Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún ún ni ara bí o tí wù ú, àti fún olúkúlùkù irú ara tirẹ̀ Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe ẹran-ara kan náà ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ènìyàn, ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ní ti ẹja, ọ̀tọ̀ sì ní tí ẹyẹ Ará ti òkè ọ̀run ń bẹ, ara ti ayé pẹ̀lú sì ń bẹ ṣùgbọ́n ògo ti òkè ọ̀run ọ̀tọ̀, àti ògo ti ayé ọ̀tọ̀ Ọ̀tọ̀ ni ògo ti òòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀ ìràwọ̀ sá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ni àjíǹde òkú A gbìn ín ní ìdibàjẹ́ a sí jì í didé ni àìdíbàjẹ́ A gbìn ín ni àìní ọlá, a sí jí i dìde ni ògo a gbìn ín ni àìlera, a sì ji í dìde ní agbára A gbìn ín ni ara ti ọkàn, a sì jí i dìde ni ara ti ẹ̀mí Bí ara tí ọkàn bá ń bẹ, ara ẹ̀mí náà sì ń bẹ Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, Ádámù ọkùnrin ìṣáàjú, alààyè ọkàn ni a dá a Ádámù ìkẹ́yìn ẹ̀mí ti ń fún ní ní ìyè Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáajú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá, ẹni erùpẹ̀ ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀ bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run Bí àwa ó sì rú àwòrán ẹni erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwa ó sì rú àworán ẹni ti ọ̀run Ará, ǹjẹ́ èyí ní mo wí pé, ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún Ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kò lé jogún àìdíbàjẹ́ Kíyesí í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà, Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìdé ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé àra àìkú wọ̀ Ṣùgbọ́n nígbá tí ará ìdíbàjẹ́ yìí bá ti gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, ti ara kíkú yìí bá sí ti gbé àìkú wọ̀ bẹ́ẹ̀ tan, nígbá náà ni ọ̀rọ̀ ti a kọ yóò ṣẹ pé, A gbé ikú mí ní iṣẹ́gun Ikú, oró rẹ dà Ikú, iṣẹgun rẹ́ dà Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀ àti agbára ẹ̀ṣẹ̀ ni òfin Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fì ìṣẹ́gun fún wá nípa Olúwa wá Jésù Kírísítì! Nítorí náà ẹ̀yín ará mi olùfẹ́ẹ̀ ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ si í ní iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, níwọn bí ẹyin ti mọ̀ pé iṣẹ́ yin kì í ṣe asán nínú Olúwa Ìkójọpọ̀ Fún Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí fi fún àwọn ìjọ Gálátíà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe Ní ọjọ́ kínní ọ̀sẹ̀, kí olukúlúkù yín fí sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jérúsálẹ́mù Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yin wá, nígbà tí èmí bá ti kọjá láàrin Makedóníà nítorí èmi yóò kọjá láàrin Makedóníà Bóyá èmi ó sì dúró pẹ̀lú yín, tàbi kí n tílẹ̀ lo àkókò òtúútúú, ki ẹ̀yin lé sìn mí ni ọ̀nà àjò mí, níbikíbi tí mo bá ń lọ Nítorí èmi kò fẹ́ kan ri yín kí èmi sì ṣe bẹ́ẹ̀ kọja lọ nítorí èmi ń retí àti dúró lọ́dọ̀ yín díẹ̀, bí Olúwa bá fẹ́ Ṣùgbọ́n èmi yóò dúró ni Éfésù títí dí Pẹ́ńtíkósìtì Nítorí pé ilẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣi sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀ta tí ń bẹ Ǹjẹ́ bí Tímótíù bá dé, ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín láìbẹ̀rù nítorí òun ń ṣé iṣẹ́ Olúwa, bí èmi pẹ̀lú ti ń ṣe Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin Ṣùgbọ́n ní ti Àpólò arákùnrin wa, mo bẹ́ẹ̀ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsìnyìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbá tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un Ẹ máa ṣọra, ẹ dúró gbọingbọin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára Ẹ máa ṣe gbogbo nínú ìfẹ́ Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ sá mọ ilé Sítéfánà, pé àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jésù ní Ákáyà, àti pé, wọn sì tí fí ará wọn fún iṣẹ́-iránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́ Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbásiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá Mo láyọ̀ fún wíwá Sítéfánà àti Fórítúnátù àti Ákáyákù nítorí èyí tí ó kù nípá tí yín wọ́n ti fí kún un Nítorí tí wọ́n tu ẹ̀mí mí lára àti tiyín nítorí náà, ẹ máa gba ìru àwọn ti ó rí bẹ́ẹ̀ Àwọn ìjọ ni Ásíà kí í yín, Àkúílà àti Pìrìsílà kí í yín púpọ̀ nínú Olúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ni ilé wọn Gbogbo àwọn arákùnrin kí í yín, ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín Ìkíni ti èmi Pọ́ọ̀lù, láti ọwọ́ èmi tìkáraàmi wá Bí ẹníkẹ́ní kò bá ní ìfẹ́ Jesu Kírísítì Olúwa, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú Máa bọ Olúwa wa! Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa kí ó wà pẹ̀lú yín! Ìfẹ́ mi wá pẹ̀lú gbogbo yín nínú Kírísítì Jésù Àmín Ọgbọ́n Láti Ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Wá Nígba tí ẹ̀mí tọ̀ yín wá, ẹ̀yin ará, kì í ṣe nípa ọ̀rọ̀ gíga àti ọgbọ́n gíga ni mo fi bá yín sọ̀rọ̀, nígbà tí èmi ń sọ̀rọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run fún un yín Nítorí tí èmi kì yóò mọ ohunkóhun nígbà ti mo wà láàrin yín bí kò ṣe Jésù Kírísítì, ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú Èmi sì tọ̀ yín wá ni àìlera, àti ní ẹ̀rù, àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwárìrì Ìwáàsu mi àti ẹ̀kọ́ mi, kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn àti ọ̀rọ̀ tí a fi ń yí ènìyàn lọ́kàn padà, bí kò ṣe nípa ìfihàn agbára Ẹ̀mí Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrin àwọn tí a pè ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó farasin, ọgbọ́n tí ó ti farapamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀ ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀, wọn kì bá tún kan ọba ògo mọ́ àgbélébùú Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé Ojú kò tíì rí, etí kò tí í gbọ́, kò sì ọkàn tí ó tí í mọ̀ènìyàn ohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ Ẹ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mi rẹ̀ Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àsírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀ Bákan náà, kò sí ẹni tó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bíkòse Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnraa rẹ̀ Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́ Èyí ni àwa ń wí, kì í e èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí Ẹnikẹ́ni tí kò bá jẹ́ ti Ẹ̀mí kò lè gba àwọn ohun tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mi Mímọ́, nítorí wọ́n jẹ́ ohun wèrè sí, kò sì le ye e, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn Ẹni tí ẹ̀mí ń ṣe ìdájọ́ ohun gbogbo, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ ni a kò ti ọwọ́ ènìyàn dá lẹ́jọ́ Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa, ti yóò fi máa kọ́ Ọ Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kírísítì Lórí Ìyapa Nínú Ìjọ Ará, èmí kò sí le bá yín sọ̀rọ̀ bí àwọn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, bí kò ṣe bí àwọn ti í ṣe tí ara, àní bí àwọn ọmọ-ọwọ́ nínú Kírísítì Wàrà ni mo ti fi bọ́ yín, kì í ṣe oúnjẹ nítorí ẹ kò í tí le gbà á nísinsin yìí náà, ẹ kò í tí le gbà a Nítorí ẹ̀yin jẹ́ ti ara síbẹ̀ Nítorí, níwọ̀n bí owú jíjẹ àti ìjà sì wà láàrin ara yín, ẹ̀yin kò ha ṣe ti ayé bí Ẹ̀yin kò ha ṣe bí ènìyàn lásán bí Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn lásán bí Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ba ń sọ pé, Èmi ń tẹ̀lé Pọ́ọ̀lù, àti ti ẹlòmíràn tún wí pé, Èmi ń tẹ̀lé Àpólò Jú gbogbo rẹ̀ lọ, kí ni Àpólò ha jẹ́, kí ni Pọ́ọ̀lù sì jẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lásán, nípaṣẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti fi fún olukúlúkù Èmi gbìn, Àpólò ń bomirin ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni ń mú ìbísí wá Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni tí ó ń gbìn nǹkan kan, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹni tí ń bomirin bí kò ṣe Ọlọ́run tí ó ń mú ìbísí wá Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bomi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó A ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ ni, ẹ̀yin pàápàá sì jẹ́ ọgbà ohun ọ̀gbìn fún Ọlọ́run, kì í ṣe fún wa, ilé Ọlọ́run ni yín, kì í ṣe ilé tiwa Nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run tí fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀, ẹlòmíràn sì ń mọ lé e, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù kíyèsára bí yóò ṣe mọ ọ́n lé e Nítorí kò sí ẹlòmíràn tó le fi ìpìlẹ̀ tòótọ́ mìíràn lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀ àní Jésù Kírísítì ni ìpìlẹ̀ náà Ǹjẹ́ bí ẹnikẹ́ni bá fí wúrà, fàdákà, òkúta olówó-iyebiye, igi, koríko, àgékù koríko mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fi hàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olùkúlùkú ṣe wò Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀ Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù Ṣùgbọ́n òun tìkárarẹ̀ ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n bí ìgbà tí ènìyàn bá la àárin iná kọjá Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́ Pé Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín Bí ẹnikẹ́ni bá ba tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run jẹ́, òun ni Ọlọ́run yóò parun nítorí pé mímọ́ ni tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run, èyí tí ẹ̀yín jẹ́ Kí ẹnikẹ́ni, má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ mọ́ Bí ẹnikẹ́ni yín nínú ayé yìí ba rò pé òun gbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó di òmùgọ̀ kí ó bá a le è gbọ́n Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ lọ́dọ̀ Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, Ẹni ti tí ó mu àwọ̀n ọlọgbọ́n nínú àrékerèke wọn lẹ́ẹ̀kan síi, Olúwa mọ̀ èrò inú àwọn ọlọ́gbọ́n pé, asán ní wọn Nítorí kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣògo nínú ènìyàn Nítorí tí yín ni ohun gbogbo Ìbá ṣe Pọ́ọ̀lù, tàbí Àpólò, tàbí Kéfà, tàbí ayé tàbí ìyè, tàbí ikú, tàbí ohun ìsinsinyìí, tàbí ohun ìgbà tí ń bọ̀ ti yín ni gbogbo wọn Ẹ̀yin sì ni ti Kírísítì Kírísítì sì ni ti Ọlọ́run Àwọn Àpósítélì Kírísítì Nítorí náà, ṣe ló yẹ kí ènìyàn máa wò wá gẹ́gẹ́ bí ìranṣẹ́ àti ìríjú tí a fún ni oore-ọfẹ́ láti mọ Kírísítì tí a fún ní oore-ọ̀fẹ́ láti mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run Òun kan náà tí ó tọ́ fún ìríjú pẹ̀lú, ni kí ó jẹ́ olóòótọ́ Èmí kò tilẹ̀ bìkítà pé, ẹ̀yin dá mi lẹ́jọ́, nítòótọ́, èmi kò tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́ Nítorí tí ẹ̀rí-ọkàn mi kò dá mi ní ẹ̀bi ṣùgbọ́n a kò ti ipa èyí dá mi láre, ṣùgbọ́n Olúwa ni ẹni tí ń ṣe ìdàjọ́ mi Nítorí náà, kí ẹ má ṣe se ìdájọ́ ohukóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó farasin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olukúlukù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ̀dọ́ Ọlọ́run Ẹ kíyèsí i pé, mo ti fi ara mi àti Àpólò ṣe àpẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe titorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà Tí ìwọ ba sì gbà á, è é ti ṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á Báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín tí a ó sì máa jọba pẹ̀lú yín! Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa àpósítélì hàn ní ìkẹyin bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítori tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn ańgẹ́lì ati gbogbo ayé Àwa jẹ́ asiwèrè nítorí Kírísítì, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú Kírísítì! Àwa jẹ́ aláìlera, ṣùgbọ́n ẹ̀yín jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ẹni àyẹ́sí, àwa jẹ ẹni ẹ̀gàn! Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òùngbẹ, a wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan Tí a ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́, wọn ń gàn wa, àwa ń súre, wọn ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń forítì i Wọn ń kẹ́gàn wa, àwa ń bẹ̀bẹ̀ Títí di ìsinsinyìí ni a ti wà bí ohun ẹ̀gbin ayé, bí orí àkìtàn gbogbo ayé Èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí láti fi dójútì yín, ṣùgbọ́n láti kìlọ̀ fún un yín bí àwọn ọmọ mi tí mo yàn fẹ́ Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbààrún olùkọ́ni nínú Kírísítì, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀ nítorí nínú Kírísítì Jésù ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìyìn rere Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi Nítorí náà ni mo ṣe rán Tìmótíù sí i yín, ẹni tí í ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Olúwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọ̀nà mi tí ó wà nínú Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo Mo mọ̀ pé àwọn mìíràn nínú yín tó ya onígbéraga ènìyàn, tí wọn ń rò pé ẹ̀rù ń bà ni láti wá sọ́dọ̀ yín láti ṣe ẹ̀tọ́ fún un yín Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yín wá ní àìpẹ́ yìí, bí Olúwa bá fẹ́ èmi yóò ṣe ìwádìí bí àwọn agbéraga yìí se ń sọ̀rọ̀ àti agbára tí wọ́n ní Nítorí ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀, bí kò ṣe nínú agbára Èwo ni ẹ yàn Kí ń wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú pàsán, tàbí ni ìfẹ̀, àti ẹ̀mí tútù Ẹ Yọ Alágbèrè Ọkùnrin Kúrò Ìròyìn rẹ ń tàn kalẹ̀ pé ìwà, àgbérè wa láàrin yín, irú àgbérè tí a kò tilẹ̀ gbúròó rẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà pé, ẹnìkan nínú yín ń fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀ Ẹ̀yin ń se ìgberaga, kí ni ṣe tí ojú kò tì yín, kí ẹ sì kún fún ìbànújẹ́, kí ẹ sì rí i pé ẹ yọ ọkùnrin náà tí ó hu ìwà yìí kúrò láàrin àwọn ọmọ ìjọ yín Lóòtọ́ èmi kò sí láàrin yín, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí àti pé, ní orúkọ Olúwa Jésù Kírísítì, mo tí ṣe ìdájọ̀ lórí irú ẹni bẹ́ẹ̀, bí ẹni pé mo wá láàrin yín Ní orúkọ Jésù Kírísítì Nígbà tí ẹ̀yin bá péjọ, àti ẹ̀mí mi, pẹ̀lú agbára Jésù Kírísítì Olúwa wa Kí ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ lé sátanì lọ́wọ́ fún ìparun ara, kí ó baà le gba ẹ̀mí là ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì Ìfọ́nnú yín kò dára Ẹ̀yin kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní i mú gbogbo ìyẹ̀fun di wíwú Nítorí náà ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò nínú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ìyẹ̀fun titun, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà Nítorí à ti fi ìrekọjá wa, àní Kírísítì ni a ti pa láti fi ṣe ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa àjọ náà mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àrankan àti ìwà búburú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà òtítọ́ àti òdodo Nígbà tí mo kọ̀wé ṣáájú sí i yín, mo sọ fún yín pé, kí ẹ má ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbérè ènìyàn Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀ ń kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ayé yìí, tí wọn ń gbé ìgbé ayé wọn nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbérè, àti àwọn olójúkòkòrò tí ń rẹ́ ni jẹ, àwọn olè àti àwọn abọ̀rìṣà Nítorí ó dájú pé ẹ̀yin gbọdọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti yẹra fún wọn Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ń wí nínú ìwé sí i yín pé, ẹ kò gbọdọ̀ darapọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó bá pe ara rẹ̀ ni arákùnrin, ṣùgbọ́n tí ó fi ẹ̀ṣẹ̀ àgbérè tàbí wọ̀bìà, ìbọ̀rìṣà àti ẹlẹ́gàn tàbí ìmutípara àti alọ́nilọ́wọ́gbà Ẹ má ṣe bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ oúnjẹ pọ̀ rárá Kì í ṣe iṣẹ́ mi láti máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí wọn kò sí nínú ìjọ Dájúdájú iṣẹ́ tiwa ni láti ṣe ìdájọ́ àti láti fi ọwọ́ líle mú àwọn tí ń bẹ nínú ìjọ Ọlọ́run nìkan ni onídájọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ Ẹ lé àwọn ènìyàn búburú náà kúrò láàrin yín Ìyanjú Èdè-àìyedè Láàrin Àwọn Onígbàgbọ́ Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ni èdè-àìyedè sí ẹnikejì rẹ̀, ó ha gbọdọ̀ lọ pè é lẹ́jọ́ níwájú àwọn aláìsòótọ́ bí, bí kò se níwájú àwọn ènìyàn mímọ́ Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpaṣẹ̀ yín ni a ti ṣe ìdájọ́ ayé, kí ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèkéé wọ̀nyí láàrin ara yín Ẹ kò mọ̀ pé àwa ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn ańgẹ́lì ní Mélòómélòó àwọn nǹkan tó wà nínú ayé yìí Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ẹ yan àwọn tí ó kéré jù nínú ìjọ láti dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín, Ṣe ó see se kí a máa rín ẹnìkan láàrin yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe idájọ́ èdè àìyedè láàrin àwọn onígbàgbọ́ Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́ ! Ǹjẹ́ nísinsinyìí, àbùkù ni fún un yín pátapáta pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́ Kí ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà Kí ní dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìsòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run Kí a máa tàn yín jẹ kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mútí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí ṣùgbọ̀n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jésù Kírísítì Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa Ohun gbogbo ní ó yẹ fún mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi, ṣùgbọ́n èmi kì yóò jẹ́ kí a fi mi ṣe olórí ohunkóhun Oúnjẹ fún inú àti inú fún oúnjẹ, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò fi òpin sí méjèèjì, ara kì í ṣe fún ìwà àgbérè síṣe, ṣùgbọ́n fún Olúwa, àti Olúwa fún ara náà Nínú agbára rẹ̀, Ọlọ́run jí Olúwa dìde kúrò nínú òkú bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò jí àwa náà dìde Ṣé ẹ kò tilẹ̀ mọ̀ pé ara yín gan an jẹ́ ẹ̀yà ara Kírísítì fún ara rẹ̀ Ǹjẹ́ tí ó ba jẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ó yẹ kí ń mú ẹ̀yà ara Kírísítì kí ń fi ṣe ẹ̀yá ara àgbérè bí Kí a má rí i! Tàbí ẹ kò mọ̀ pé bí ẹnìkan bá so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àgbérè ó jẹ́ ara kan pẹ̀lú rẹ̀ Nítorí a tí kọ ọ́ wí pé, Àwọn méjèèjì ni yóò di ara kan ṣoṣo Ṣùgbọ́n ẹni ti ó dápọ̀ mọ́ Olúwa di ẹ̀mí kan náà pẹ̀lú rẹ̀ Ẹ máa sá fún àgbérè Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ènìyàn ń dá wà lóde ara, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbérè ń ṣe sí ara òun tìká ara rẹ̀ Tàbí, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín ni tẹ́ḿpìlì Ẹ̀mí Mímọ́, ti ń bẹ nínú yín, ti ẹ̀yin ti gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run Ẹ̀yin kì í ṣe ti ara yín, nítorí a ti rà yín ni iye kan Nítorí náà ẹ yìn Ọlọ́run lógo nínú ara yín, àti nínú ẹ̀mí yín, tì í ṣe ti Ọlọ́run Ìgbéyàwó Ní báyìí, nítorí àwọn ohun tí ẹ ṣe kọ̀wé Ó dára fún ọkùnrin kí ó máa gbéyàwó Ṣùgbọ́n nítorí àgbérè pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ̀ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan gbéyàwó tirẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni kí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní ọkọ tirẹ̀ Kí ọkùnrin kí ó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ìyàwó rẹ̀ fún ún, kí ìyàwó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ọkọ fún ọkọ rẹ̀ Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ọkọ rẹ̀ Bákan náà ni ọkùnrin tí ó gbéyàwó kò ní àṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ìyàwó rẹ̀ Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ẹ̀tọ́ tọkọtaya wọ̀nyí dun ara yín, bí kò ṣe nípa ìfìmọ̀sọ̀kan, kí ẹ̀yin lè fi ara yín gún ààwẹ̀ àti àdúrà, kí ẹ̀yin sì tún jùmọ̀ pade, lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ ara wọn kí sátanì má baà dán wọn wò nítorí àìlèmáradúró wọn Mo sọ èyí fún un yín bí ìmọ̀ràn ní kì í ṣe bí àṣẹ Ó wù mí kí olúkúlùkù dàbí èmi láìgbéyàwó, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn kò le jẹ́ bákan náà, Ọlọ́run fún olúkúlùkù ènìyàn ní ẹ̀bún tírẹ̀, ọ̀kan bí irú èyi àti èkejì bí irú òmíràn Nítorí náà, mo wí fún àwọn àpọ́n àti opó pé, ó sàn kí wọn kúkú wà gẹ́gẹ́ bí èmi tí wà Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá lè mú ara dúró, kí wọn gbéyawó tàbí kí wọ́n fẹ́ ọkọ, nítorí pé ó sàn láti gbéyáwò jù láti ṣe ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ lọ Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa Obìnrin kò gbọdọ̀ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ Ṣùgbọ́n tí ó bá kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀ jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó padà sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀ ti ó fi sílẹ̀ àti ọkùnrin pàápàá kò gbọdọ̀ fi ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Mo fẹ́ fi àwọn àmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Tí ó bá sì jẹ́ obìnrin ló fẹ́ ọkọ tí kò gbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí ọkọ náà ń fẹ́ kí obìnrin yìí dúró tí òun, aya náà kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Nítorí pé ó ṣe é ṣe kí a lè mú ọkọ tí kò gba Kírísítì gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa aya tí í ṣe onígbàgbọ́, a sì le mú ìyàwó tí kò gba Kírísítì gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́ Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ṣe é ṣe kí àwọn ọmọ wọn di mímọ́ Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin tí i ṣe aláìgbàgbọ́ náà bá fẹ́ láti lọ, jẹ́ kí ó máa lọ Onígbàgbọ́ ọkùnrin tàbí obìnrin náà kò sí lábẹ́ idè mọ́ Ọlọ́run ti pè wá láti gbé ní àlààfíà Báwo ni ẹ̀yin aya ṣe mọ̀ pé ẹ̀yin ni yóò gba ọkọ yín là Bákan náà ni a lè wí nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́ pé, kò sí ìdánilójú pé aya aláìgbàgbọ́ le yípadà láti di onígbàgbọ́ nípa dídúró ti ọkọ Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù máa gbé ìgbé ayé tí Ọlọ́run ń fẹ́ yín fún, àti nínú èyí tí Olúwa pè é sí Ìlànà àti òfin mi fún gbogbo ìjọ ni èyi Ǹjẹ́ ọkùnrin kan há ti kọlà nígbà tí a pè é Kí ó má sì ṣe di aláìkọlà Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é Kí ó ma ṣe kọlà Ìkọlà kò jẹ́ nǹkan àti àìkọlà kò jẹ́ nǹkan, bí kò ṣe pípa òfin Ọlọ́run mọ́ Ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa ṣe iṣẹ́ tí ó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí Ọlọ́run tó pé é sínú ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Ǹjẹ́ ẹrú ni ọ́ bí nígbà ti a pè ọ́ Má ṣe kà á sí Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá le di òmìnira, kúkú ṣe èyí nì Tí ó bá jẹ́ ẹrú, ti Olúwa sì pé ọ, rántí pé Kírísítì ti sọ ọ́ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ agbára búburú ti ẹ̀ṣẹ̀ Tí ó bá sì ti pé ọ̀ nítòótọ́ tí ó sì ti di òmìnira, ó ti di ẹrú Kírísítì A sì ti rá yín ní iyè kan, nítorí náà ẹ má ṣe di ẹrú ènìyàn Ará, jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn, nínú èyí tí a pè é, kí ó dúró nínú ọ̀kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run Ṣùgbọ́n nípa ti àwọn wúndíá èmi kò ní aṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo wí fún yín ní ìdájọ́ bí ẹni tí ó rí àánú Olúwa gbà láti jẹ́ olódodo Nítorí náà mo rò pé èyí dára nítorí wàhálà ìsinsinyìí, èyi nì ni pé o dára fún ènìyàn kí ó wà bí ẹ ṣe wà Ṣùgbọ́n tí ó bá ti gbéyàwó tàbí tí ó bá ti lákòókó, ẹ má ṣe kọ ara yín sílẹ̀, nítorí èyí tí mo wí yìí Ṣùgbọ́n tí kò bá sì tí ì gbéyàwó, tàbí fẹ́ ọkọ, má ṣe sáre láti ṣe bẹ́ẹ̀ lákókó yìí Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá gbé ìyàwó ìwọ kò dẹ́sẹ̀, bí a bá gbé wúndíá ní ìyàwó òun kò dẹ́sẹ̀ Ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó bá gbé ìyàwó yóò dojú kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nípa ti ara ṣùgbọ́n mo dá a yín sí Òun ti mo ń wí ará, ni pé kúkúrú ni àkókò, láti ìsinsinyìí lọ, ẹni tí ó ni aya kí ó dàbí ẹni tí kò ní rí àwọn tí ń sọkún, bí ẹni pé wọn kò sọkún rí, àti àwọn tí ń yọ̀ bí ẹni pé wọn kò yọ̀ rí, àti àwọn tí ń rà bí ẹni pé wọn kò ní rí, àti àwọn tó ń lo ohun ayé yìí, bí ẹni tí kò ṣe àṣejù nínú wọn nítorí àṣà ayé yìí ń kọ́ja lọ Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi siṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn ẹrù rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn, dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì Bákan náà ló rí fún obìnrin tí ó bá wà nílé ọkọ, irú ìṣòro kan náà ni ó dojú kọ Ọmọbìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa ṣàkìtiyan láti tẹ́ Olúwa lọ́rùn ní gbogbo ìwà àti ìṣe àti ní tí ẹ̀mí Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe àkíyèsí ohun púpọ̀, yóò máa wá ọ̀nà láti tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn Mo ń sọ èyí fún àǹfààní ara yín kì í ṣe láti dá yín lẹ́kun ṣùgbon kí ẹ̀yin lè gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́ kí ẹ sì lè máa sin Olúwa láìsí ìyapa ọkàn Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun kò ṣe ohun tí ó yẹ sí wúndíá rẹ̀ bí ó bá ti di obìnrin, bí ó bá sí tọ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ó ṣe bí ó tí fẹ́, òun kò dẹ́sẹ̀, jẹ́ kí wọn gbé ìyàwó Ṣùgbọ́n ẹni tí ó dúró sinsin ni ọkàn rẹ̀, tí kò ní àìgbọ́dọ̀ má ṣe, ṣùgbọ́n tí ó ní agbára lóri ìfẹ́ ara rẹ̀, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn rẹ̀ pé, òun ó pa wúndíá ọmọbìnrin òun mọ́, yóò ṣe rere Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹni tí ó fi wúndíá ọmọbìnrin fún ni ní ìgbéyàwó, ó ṣe rere ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi fún ni ní ìgbéyàwó ṣe rere jù lọ A fi òfin dé obìnrin níwọ̀n ìgbà tí òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ wà láàyè, bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn, tí ó bá wù ú ó sì gbọdọ̀ jẹ́ ti Olúwa Ṣùgbọ́n nínú èrò tèmi obìnrin náà yóò ní ayọ̀ púpọ̀, tí kò bá ṣe ìgbéyàwó mìíràn mọ́ Mo sì rò pé mo ń fún un yín ní àmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run nígbà tí mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí Oúnjẹ Tí A Fi Rúbọ Sí Òríṣà Ní ìsinsinyìí, nípa tí oúnjẹ ti a fi rúbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé gbogbo wa ni a ní ìmọ̀, ìmọ̀ a máa fẹ́ mu ní gbéraga, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ní i gbéni ró Bí ẹnkẹ́ni bá ró pé òun mọ ohun kan, kò tí ì mọ̀ bí ó ti yẹ kí ó mọ̀ Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run nítòótọ́, òun ni ẹni tí a ṣí lójú sí ìmọ̀ àti òye Ọlọ́run Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a jẹ àwọn oúnjẹ ti a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà bí Láì ṣe àní àní, gbogbo wá mọ̀ pé àwọn ère òrìṣà kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ohun asán ni wọn ni ayé A sì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run kansoso ní ń bẹ, kò sì sí Ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ Ọlọ́run kékèké mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan soso Jésù Kírísítì, nípaṣẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípaṣẹ̀ rẹ̀ Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn lo mọ èyí Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn tí ó ti ń bọ̀rìṣà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ títí di ìsinsinyìí jẹ ẹ́ bí ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà àti ẹ̀rì-ọkàn wọn tí ó ṣe àìlera sì di aláìmọ́ Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò mú wa súnmọ́ Ọlọ́run, nítorí pé kì í ṣe bí àwa bá jẹun ni àwa buru julọ tàbí nígbà tí a kò jẹ ni àwa dára jùlọ Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsí ara gidigidi nípa ìlò òmìnira yín kí ẹ má baà mú kí àwọn arákùnrin mìíràn tí í se onígbàgbọ́, tí ọkàn wọn ṣe aláìlera, subú sínú ẹ́sẹ̀ Ẹ kíyèsára, nítorí bi ẹnìkan ba rí i ti iwọ ti o ni ìmọ̀ bá jókòó ti oúnjẹ ní ilé òrìṣà, ǹjẹ́ òun kò ha ni mú ọkàn le, bi ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ bá ṣe aláìlera, lati jẹ oúnjẹ tí a fi rúbọ sí òrìsà Nítorí náà, nípa ìmọ̀ rẹ ni arákùnrin aláìlera náà yóò ṣe ṣègbé, arákùnrin ẹni tí Kírísítì kú fún Bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀ sí arakùnrin rẹ̀ tí ẹ sì n pá ọkàn àìlera wọn lára, ẹ̀yìn ǹ dẹ́sẹ̀ sí Kírísítì jùlọ Nítorí nàá, bí ẹran tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà bá máa mú arákùnrin mi dẹ́ṣẹ̀, èmi kì yóò jẹ́ ẹran mọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè, nítorí n kò fẹ́ kí arákùnrin mi ṣubú sìnù ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Ẹ̀tọ́ Àpósítélì Èmi kò ha ni òmìnira bí Èmi kò ha ń ṣe àpósítélì bí Èmi kò ha ti rí Jésù Olúwa bí Ẹ̀yìn ha kọ́ ní èrè iṣẹ́ mi nínú Olúwa bí Ní ìrònú àwọn ẹlòmíràn, èmi kì í ṣe àpósítélì Dájúdájú àpósítélì ni mo jẹ́ fún un yín, tí n kì bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn Nítorí èdìdì iṣẹ́ àpósítélì mi ni ẹ̀yin jẹ́ nínú Olúwa Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ Àpósítélì mi Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í se onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn Àpósítélì mìíràn Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kéfà Ṣé kìkì Bánábà àti èmi ló yẹ kí a máa ṣisẹ́ bọ́ ara wa ni Ta ni ó síṣẹ́ ogun nígbà tí ó sanwo ara rẹ̀ Ta ní gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ nínú èso rẹ̀ , Tàbí ta ní ń bọ ọ̀wọ́-ẹran tí kì í sí ì jẹ nínú wàrà ọ̀wọ́-ẹran Èmi ha sọ nǹkan wọ̀nyí bí ènìyàn Tàbí òfin kò wí bákan náà bì Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mósè, ni a tí kọ ọ́ pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń pakà nínú oko rẹ̀ lẹ́nu mọ́ Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a se kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìretí láti ní ipin nínú ìkórè A ti fún irúgbìn èso ẹ̀mí sìnú ọkàn yín Ẹ rò pé ó pọ̀jù fún wa tàbí ẹ kà á sí àṣejù, láti béèré fún oúnjẹ àti aṣọ fún àyọrísí iṣẹ́ wa bí Bí àwọn ẹlòmírán bá ní ẹ̀tọ́ tí ìrànlọ́wọ́ sì wá láti ọ̀dọ̀ yín, àwa ha kọ́ ni ó tọ́ sí jù Ṣùgbọ́n àwa kò lo agbára yìí ṣùgbọ́n àwa faradà ohun gbogbo, kí àwa má baà ṣe ìdènà fún ìyìn rere Kírísítì Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń siṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, làti fi se ìtọ́ju ara wọn Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa se àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ Lọ́nà kan náà ni Olúwa ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé, àwọn tí ń wàásù íyìnrere kí wọn sì máa jẹ́ ní ti ìyìn rere Ṣíbẹ̀síbẹ̀ n kò ì tí ì lo iru àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí rí Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì kọ lẹ́tà yìí láti fi sọ fún un yín pé, mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà irú nǹkan bẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ yín Kí a sọ òtítọ́, ó sàn fún mi láti kú sínú ebi ju pé kí n sọ ayọ̀ tí mo ní láti wàásù nù Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìyìn rere, kì í se ohun tí mo lè máa sogo lè Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìyìn rere Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, nígbà náà Olúwa ní ẹ̀bùn pàtàkì fún mi, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe é tinútinú mi, mo ṣe àsìlò ìdanilójú tí a ní nínú mi Ní irú ipò báyìí, kí ni ẹ rò pé èrè mi ni láti jẹ́ Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìyìn rere láèná ẹnikẹ́ni lówó, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì dara pọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sí i Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn baà lè tẹ́tí sí ìwàásù ìyìn rere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kírísítì Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá , kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin , kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi baà lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí Mo ṣe èyí láti lè rí ààyè láti wàásù ìyìn rere sí wọn àti fún ìbùkún tí èmi pàápàá ń rí gbà, nígbà tí mo bá rí i pé wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn Kírísítì Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú rẹ̀ ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò kìn-ín-ní Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ baà le borí Láti borí nínú eré ìdíje, ẹ ní láti sẹ́ ara yín nínú ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó lè fá yín sẹ́yín nínú sísa gbogbo agbára yín Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́ Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run tí kò lè bàjẹ́ láéláé Nítorí náà, mo ń sá eré ìje lọ sójú àmì, kì í ṣe bí ẹni ti kò dá lóju Mò ń jà kí n lè borí, kì í ṣe bí ẹni tí ń bá afẹ́fẹ́ jà Ṣùgbọ́n èmi ń ń kó ara mi níjànu, mo sì n mú un wá sí abẹ́ ìtẹríba, pé lẹ́yìn tí mo ti wàásù fún áwọn ẹlòmíràn, nítorí ohunkóhun, kí èmi fún rara mi má se di ẹni ìtanú fún ẹ̀bùn náà Ọ̀rọ̀ Ìyè Èyí tí ó wà láti àtètèkọ́ṣe, tí àwa ti gbọ́, tí àwa ti fi ojú wa rí, tí àwa sì ti tẹjúmọ́, tí ọwọ́ wa sì ti dì mú èyí tí a kéde ní ti ọ̀rọ̀ ìyè Ìyè náà sì ti farahàn, àwa sì ti rí i, àwa sì ń jẹ́rí, àwa sì ń sọ ti ìyè àìnípẹ̀kun náà fún yín, tí ó ti ń bẹ lọ́dọ̀ Baba, tí ó sì farahàn fún wa Àwa ń sọ fún yín, èyí tí àwa ti rí, tí àwa sì ti gbọ́, kí ẹ̀yin pẹ̀lú kí ó lè ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú wa Nítòótọ́ ìdàpọ̀ wa sì ń bẹ pẹ̀lú Baba àti pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, Jésù Kírísítì Àwa sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ayọ̀ yín kí ó lè di kíkún Èyí sì ni iṣẹ́ tí àwa ti gbọ́ lẹ́nu rẹ tí àwa sì ń jẹ́ fún yín pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọ́run ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì òkùnkùn rárá Bí àwa bá wí pé àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí àwa sì ń rìn nínú òkùnkùn, àwa ń ṣèké, àwa kò sì gbé nínú òtítọ́ Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun ti ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ara wa, àti pé ẹ̀jẹ̀ Jésù Kírísítì, Ọmọ rẹ̀, wẹ̀ wá nù kùrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo Bí àwa bá wí pé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tan ara wa jẹ, òtítọ́ kò sì sí nínú wa Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ àti olódodo ni òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣododo gbogbo Bí àwa bá wí pé àwa kò dẹ́sẹ̀, àwa mú un ní èké, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí nínú wa Ẹ Má Ṣe Fẹ́ràn Ayé Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, mo kọ ìwé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ẹ̀yin má bà á dẹ́ṣẹ̀ Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá sì dẹ́ṣẹ̀, àwa ni alágbàwí lọ́dọ̀ Baba Jésù Kírísítì, olódodo nìkan Òun sì ní ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kì í tilẹ̀ ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé Àwa mọ̀ pé àwa ti wá mọ̀ ọ́n, bí àwa bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́ Ẹni tí ó bá wí pé, Èmi mọ̀ ọ́n, tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì sí nínú rẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́, lára rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́ Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń wà nínú rẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí Jésù ti rìn Ẹ̀yin olùfẹ ọ̀wọ́n, kì í ṣe òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín ṣùgbọ́n òfin àtijọ́, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe Òfin àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ náà tí ẹ̀yin tí gbọ́ Pẹ̀lúpẹ̀lú, òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín èyí tí í ṣe òtítọ́ nínú rẹ̀ àti nínú yin, nítorí òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ́ òtítọ́ sì tí ń tàn Ẹni tí o bá sì wí pé òun ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, tí o sì kóríra arákùnrin rẹ̀ sì ń bẹ nínú òkùnkùn Ẹni tí o ba fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀, o ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, kò sì sí ohun ìkọ̀sẹ̀ kan nínú rẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹni tí o bá kóríra arákùnrin rẹ̀ ń gbé nínú òkunkùn, ó sì ń rìn nínú òkùnkùn kò sì mọ ibi tí òun ń lọ, nítorí tí òkùnkùn tí fọ́ ọ lójú Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, nítorí tí a darí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ rẹ̀ Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba, nítorí tí ẹ̀yin tí mọ ẹni tí ó wà ní àtètèkọ́ṣe, Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣẹ́gun ẹni ibi náà Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọdé mi ọ̀wọ́n, nítorí ẹ̀yin ti mọ Baba Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba, nítorí ti ẹ̀yin tí mọ ẹni tí o wà ni àtètékọṣe Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, nítorí tí ẹ̀yin ni agbára, tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń gbé nínú yín, tí ẹ sì ṣẹ́gun ẹni ibi náà Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀ Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé ìfẹ́kùfẹ́ ẹni ẹ̀sẹ̀, ìfẹ́kùfẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó se kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kùfẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ìgbà ìkẹyìn ni èyí bí ẹ̀yin sì tí gbọ́ pé Aṣòdìsí-Kírísítì ń bọ̀ wá, àní nísìnsin yìí, púpọ̀ Aṣòdì-sí-Kírísítì ló ń bẹ Nípa èyí ni àwa fí mọ́ pé ìgbà ìkẹ́yìn ni èyí Wọn ti ọ̀dọ̀ wá jáde, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe ara wa Nítorí bí wọ́n bá jẹ́ ara wa, wọn ìbá bá wa dúró ṣùgbọ́n jíjáde lọ wọn fihàn pé gbogbo wọn kì í ṣe ara wa Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní ìfòróró-yàn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí-mímọ́ wá, gbogbo yín sì mọ òtítọ́ Èmi kò kọ̀wé sí yín nítorí pé ẹ̀yin kò mọ òtítọ́, ṣùgbọ́n nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, àti pé kò sí èké nínú òtítọ́ Ta ni èké Ẹni tí ó sẹ́ pé Jésù kì í ṣe Kírísítì Eléyìí ni Aṣòdìsí-Kírísítì ẹni tí ó sẹ́ Baba àti Ọmọ Ẹnikẹ́ni tí o ba sẹ́ Ọmọ, kò gba Baba ṣùgbọ́n ẹni tí o ba jẹ́wọ́ Ọmọ, ó gba Baba pẹ̀lú Ẹ jẹ́ kí èyí tí ẹ tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe máa gbé inú yín Bí èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe bá ń gbé inú yín, ẹ̀yin ó sì dúró nínú Ọmọ àti nínú Baba Èyí sì ni ìlérí náà tí ó tí ṣe fún wa, àní ìyè àìnípẹ̀kun Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé sí yín ní ti àwọn tí wọ́n fẹ́ kó o yín sìnà Ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀yin ìfóróró-yàn tí gba lọ́wọ́ rẹ̀ sì ń gbé inú yín, ẹ̀yin kò tún nílò pé kí ẹnìkan kọ yín Ṣùgbọ́n bí ìfòróró-yàn náà ti ń kọ́ yín ní ohun gbogbo tí o jẹ́ òtítọ́, tí kì í sì í ṣe èké, àní gẹ́gẹ́ bí ó sì ti kọ́ yín, ẹ máa gbé inú rẹ̀ Àti nísinsin yìí, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ẹ máa gbé inú rẹ̀, pé nígbà tí òun ó bá farahàn, kí a lè ni ìgboyà níwájú rẹ̀, kí ojú má sì tì wá níwájú rẹ̀ ni ìgbà wíwá rẹ̀ Bí ẹ̀yin ba mọ́ pé olódodo ni òun, ẹ mọ pé a bí olúkúlùkù ẹni tí ń ṣe òdodo nípa rẹ̀ Fẹ́ràn Ọmọnìkéjì Rẹ Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba fi fẹ́ wa, tí a fi ń pè wá ní Ọmọ Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni a sáà jẹ́ Nítorí èyí ni ayé kò ṣe mọ̀ wá, nítorí tí kò mọ̀ ọ́n Olùfẹ́, ọmọ Ọlọ́run ni àwa ń ṣe nísinsin yìí, a kò ì tí i fihàn bí àwa ó ti rí àwa mọ̀ pé, nígbà tí òun ba farahàn, àwa yóò dàbí rẹ̀ nítorí àwa yóò rí i, àní bí òun tí rí Olúkúlùkù ẹni tí o ba sì ní ìrètí yìí nínú rẹ̀, ń wẹ ara rẹ̀ mọ́, àní bí òun ti mọ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ó ń rú òfin pẹ̀lú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ni rírú òfin Ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òun farahàn láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò ẹ̀ṣẹ̀ kò sì sí nínú rẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí o ba ń gbé inú rẹ̀ kì í dẹ́ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń dẹ́ṣẹ̀ kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo Ẹni tí ó ba ń dẹ́ṣẹ̀ tí èṣù ni nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni Èṣù ti ń dẹ́ṣẹ́ Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí o lè pa iṣẹ́ Èṣù run Ẹnikẹ́ni tí a ti ipa Ọlọ́run bí, kì í dẹ́ṣẹ̀ nítorí tí irú rẹ̀ ń gbé inú rẹ̀ kò sì lè dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé a ti ti ipa Ọlọ́run bí i Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ Èṣù ẹníkẹni í kò ba ń ṣe òdodo, àti ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọ́run Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ̀yin tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé ki àwa fẹ́ràn ara wa Kì í ṣe bí Káínì, tí í ṣe ẹni búburú, tí o sì pa arákùnrin rẹ̀ Nítorí kín ni ó sì ṣe pa á Nítorí tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́ búburú ṣùgbọ́n tí arakúnrin rẹ̀ sì jẹ́ òdodo Kì ẹnu má ṣe yà yín, ẹ̀yin ará mi, bí ayé bá kóríra yín Àwa mọ̀ pé àwa tí rékọjá láti inú ikú sínú ìyè, nítorí tí àwa fẹ́ràn àwọn ará Ẹni tí kò ba ni ìfẹ́ ó ń gbé inú ikú Ẹnikẹ́ni tí ó ba kórìíra arákùnrin rẹ̀ apànìyàn ni ẹ̀yin sì mọ́ pé kò sí apànìyàn tí o ni ìyè àìnípẹ̀kun láti máa gbé inú rẹ̀ Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀ Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́ Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì dá ara wa lójú níwájú rẹ̀ Nínú ohunkóhun tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi nítorí pé Ọlọ́run tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo Olùfẹ́, bí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, ǹjẹ́ àwa ni ìgboyà níwájú Ọlọ́run Àti ohunkòhun tí àwa bá béèrè, ni àwa ń rí gbà lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí àwa ń pa òfin rẹ̀ mọ́, àwa sì ń ṣe àwọn nǹkàn tí ó dára lójú rẹ̀ Èyí sì ni òfin rẹ̀, pé kí àwa gba orúkọ Jésù Kírísítì Ọmọ rẹ̀ gbọ́, kí a sì fẹ́ràn ara wá gẹ́gẹ́ bí ó tí fi òfin fún wa Ẹni tí ó bá sì pa òfin rẹ̀ mọ́ ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú rẹ̀ Àti nípa èyí ni àwa mọ̀ pé ó ń gbé inú wa, nípa Ẹ̀mí tí ó fi fún wa Ẹ Dán Àwọn Ẹ̀mí Wò Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé Èyí ni ẹ ó fi mọ Ẹ̀mí Ọlọ́run gbogbo ẹ̀mí tí ó ba jẹ́wọ́ pé, Jésù Kírísítì wá nínú ara, ti Ọlọ́run ni Gbogbo ẹ̀mí tí kò si jẹ́wọ́ pé Jésù Kírísítì wà nínú ara, kì í ṣe tí Ọlọ́run èyí sì ni ẹ̀mí aṣòdì-sí-kírísítì náà, tí ẹ̀yin ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, àti nísinsin yìí ó sì tí de sínú ayé Ẹ̀yin ọmọ mi, ti Ọlọ́run ni yín, ẹ̀yin sì tí ṣẹ́gun wọn nítorí ẹni tí ń bẹ nínú yin tóbi jú ẹni tí ń bẹ nínú ayé lọ Tí ayé ni wọ́n, nítorí náà ni wọn ṣe ń sọ̀rọ̀ bí ẹni ti ayé, ayé sì ń gbọ́ tí wọn Ti Ọlọ́run ni àwa ẹni tí ó bá mọ Ọlọ́run, ó ń gbọ́ tiwa ẹni tí kì í ṣe ti Ọlọ́run kò ni gbọ́ ti wa Nípa èyí ni àwa mọ ẹ̀mí òtítọ́, àti ẹ̀mí èké Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí a fẹ́ràn ara wa nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá àti gbogbo ẹni tí ó bá ní ìfẹ́, a bí i nípa ti Ọlọ́run, ó sì mọ Ọlọ́run Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọ́run nítorí pé ìfẹ́ ni Ọlọ́run Nípa èyí ni a gbé fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nínú wa, nítorí tí Ọlọ́run rán ọmọ bíbí rẹ̀ nìkan ṣoṣo sì ayé, kí àwa lè yè nípasẹ̀ rẹ̀ Nínú èyí ni ìfẹ́ wà, kì í ṣe pé àwa fẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n òun fẹ́ wá, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa Olùfẹ́, bí Ọlọ́run ba fẹ́ wa bayìí, ó yẹ kí a fẹ́ràn ara wa pẹ̀lú Ẹnikẹ́ni kò ri Ọlọ́run nígbà kan rí Bí àwa bá fẹ́ràn ara wa, Ọlọ́run ń gbé inú wa, a sì mú ìfẹ́ rẹ̀ pé nínú wa Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń gbé inú rẹ̀, àti Òun nínú wa, nítorí tí ó ti fi Ẹ̀mí rẹ̀ fún wa Àwa tí rí, a sì jẹ́rìí pé Baba rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ Olùgbàlà fún aráyé Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jésù Ọmọ Ọlọ́run ni, Ọlọ́run ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú Ọlọ́run Báyìí ni àwa mọ̀, tí a sì gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́ Ìfẹ́ ni Ọlọ́run ẹni tí ó bá sì ń gbé inú ìfẹ́ ó ń gbé inú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀ Nínú èyí ni a mú ìfẹ́ tí ó wà nínú wa pé, kí àwa bà á lè ni ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́ nítorí pé bí òun tí rí, bẹ́ẹ̀ ni àwa sì rí ni ayé yìí Ìbẹ̀rù kò sí nínú ìfẹ́ ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó pé ń lé ìbẹ̀rù jáde nítorí tí ìbẹ̀rù ni ìyà nínú Ẹni tí ó bẹ̀rù kò pé nínú ìfẹ́ Àwa fẹ́ràn rẹ̀ nítorí òun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, Èmi fẹ́ràn Ọlọ́run, tí ó sì kórìíra arákùnrin rẹ̀, èké ni nítorí ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ tí ó rí, báwo ni yóò tí ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run tí òun kò rí Òfin yìí ni àwa sì rí gbà láti ọwọ́ rẹ̀ wá, pé ẹni tí ó bá fẹ́ràn Ọlọ́run kí ó fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Ìgbàgbọ̀ Nínú Ọmọ Ọlọ́run Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jésù ni Kírísítì, a bí i nípa ti Ọlọ́run àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn Ẹni tí ó bi nì, ó fẹ́ràn ẹni tí a bí nípaṣẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run, tí a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́ Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa pa òfin rẹ̀ mọ́ òfin rẹ̀ kò sì nira, nítorí olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run, ó ṣẹ́gun ayé èyí sì ni ìṣẹ́gun tí ó ṣẹ́gun ayé, àní ìgbàgbọ́ wa Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé, bí kò ṣe ẹni tí ó gbàgbọ́ pé Ọmọ́ Ọlọ́run ni Jésù jẹ́ Èyí ni ẹni tí ó wá nípa omi àti ẹ̀jẹ̀, Jésù Kírísitì, kì í ṣe nípa omi nìkan, bí kò ṣe nípa omi àti ẹ̀jẹ̀ Àti pé Ẹ̀mí ni ó sì ń jẹ̀rìí, nítorí pé òtítọ́ ni Ẹ̀mí Nítorí pé àwọn mẹ́ta ni ó ń jẹ́rìí Ẹ̀mí, omi, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wà ni ìṣọ̀kan Bí àwa ba ń gba ẹ̀rí ènìyàn, ẹ̀rí Ọlọ́run tóbi jù nítorí ẹ̀rí Ọlọ́run ni èyí pé, Ó tí jẹ́rìí ní ti Ọmọ rẹ̀ Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́, ó ni ẹ̀rí nínú ara rẹ̀ ẹni tí kò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó ti mú un ni èké nítorí kò gba ẹ̀rí náà gbọ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ní ti Ọmọ rẹ̀ Ẹ̀rí náà sì ni èyí pé Ọlọ́run fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, ìyè yìí sì ń bẹ nínú Ọmọ rẹ̀ Ẹni tí ó bá ni Ọmọ, ó ni ìyè ẹni tí kò bá sì ni Ọmọ Ọlọ́run, kò ní ìyè Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín, àní sí ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́ kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun, àní fún ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́ Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tí wa, ohunkóhun tí àwa bá béèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà Bí ẹnikẹ́ni bá rí arákùnrin rẹ̀ tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú, òun yóò béèrè, Ọlọ́run yóò sì fún un ni ìyè, àní, fún àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú Ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ sì ikú èmi kò wí pé ki òun gbàdúrà fún èyí Gbogbo aìṣòdodo ni ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ tí kì í ṣe sí ikú Àwá mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí a bí nípa ti Ọlọ́run kì í dẹ́ṣẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run a pá ara rẹ̀ mọ́, ẹni búburú kò ní lè fọwọ kàn án Àwa mọ̀ pé tí Ọlọ́run ni wá, àti gbogbo ayé ni ó wà lábẹ́ agbára ẹni búburú náà Àwa sì mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run dé, ó sì tí fi òye fún wa, kí àwa lè mọ ẹni tí í ṣe òtítọ́, àwa sì ń bẹ nínú ẹni tí í ṣe òtítọ́, àní, nínú Ọmọ rẹ̀, Jésù Kírísítì Èyí ni Ọlọ́run òtítọ́, àti ìyè àìnípẹ̀kun Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú òrìṣà Àdóníjà Fi Ara Rẹ̀ Jẹ Ọba Nígbà tí Dáfídì ọba di arúgbó, ọjọ́ rẹ̀ sì pọ̀, ara rẹ̀ kò le è móoru bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n da ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ bò ó Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, Ẹ jẹ́ kí a wá ọ̀dọ́mọbìnrin wúndíá kan kí ó dúró ti ọba, kì ó sì máa tọ́jú rẹ̀ Kí ó dùbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀ kí ara ọba Olúwa wa lè móoru Nígbà náà ni wọ́n lọ jákèjádo ilẹ̀ Ísírẹ́lì láti wá ọ̀dọ́mọbìnrin arẹwà, wọ́n sì rí Ábíságì, ará Ṣúnémù, wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọba Ọmọbìnrin náà rẹwà gidigidi ó sì ń ṣe ìtọ́jú ọba, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n ọba kò sì bá a lò pọ̀ Àdóníjà ẹni tí ìyá rẹ̀ ń ṣe Hágátì sì gbé ara rẹ̀ ga, ó sì wí pé, Èmi yóò jẹ ọba Ó sì sètò kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́sin, pẹ̀lú àádọ́ta ọkùnrin láti máa sáré níwájú rẹ̀ Àdóníjà sì gbérò pẹ̀lú Jóábù, ọmọ Ṣérúyà àti Ábíátarì àlùfáà, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un Ṣùgbọ́n Ṣádókù àlùfáà, Bẹ́náyà ọmọ Jóhóíádà, Nátanì wòlíì, Ṣímè àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Rélì àti olórí ogun Dáfídì ni kò darapọ̀ mọ́ Àdóníjà Nígbà náà ni Àdóníjà fi àgùntàn àti màlúù àti ẹran ọ̀sìn tí ó sanra rúbọ níbi òkúta Sóhélétì tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Énrógélì Ó sì pe gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ ọba, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ ọba Ṣùgbọ́n kò pe Nátanì Wòlíì tàbí Bénáyà tàbí àwọn olórí tàbí Sólómónì arákùnrin rẹ̀ Nígbà náà ni Nátanì bèrè lọ́wọ́ Bátíṣébà, ìyá Sólómọ́nì pé, Ǹjẹ́ ìwọ kò gbọ́ pé Àdóníjà, ọmọ Hágítì ti jọba láìjẹ́ pé Dáfídì Olúwa wa mọ̀ síi Ǹjẹ́ nísinsin yìí, jẹ́ kí èmi gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn bí ìwọ ṣe lè gba ẹ̀mí rẹ là àti ẹ̀mí ọmọ rẹ Sólómónì Lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ọba, kí o sì wí fún un pé, Olúwa mi ọba, ǹjẹ́ ìwọ kò búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé, Dájúdájú Sólómónì ọmọ rẹ ni yóò Jọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi Èéṣe nígbà náà tí Àdóníjà fi jọba Níwọ̀n ìgbà tí ìwọ sì wà níbẹ̀, tí o sì ń bá ọba sọ̀rọ̀ èmi yóò wá, láti wádìí ohun tí o ti sọ Bẹ́ẹ̀ ni Bátíṣébà lọ rí ọba ní inú yàrá rẹ̀, ọba sì gbó gidigidi níbi tí Ábíságì ará Súnémù sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba Bátíṣébà sì tẹríba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba Ọba sì béèrè pé, Kí ni ìwọ ń fẹ́ Ó sì wí fún ọba pé, Olúwa mi ìwọ fúnra rẹ fi Olúwa Ọlọ́run rẹ búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé Sólómónì ọmọ rẹ yóò jọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Àdóníjà ti di ọba, ìwọ, ọba Olúwa mi, kò sì mọ̀ nípa rẹ̀ Òun sì ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ màlúù, àti ẹran tí ó ní ọ̀rá, àti àgùntàn rúbọ, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, àti Ábíátarì àlùfáà àti Jóábù balógun, ṣùgbọ́n kò sì pe Sólómónì ìránṣẹ́ rẹ Olúwa mi ọba, ojú gbogbo Ísírẹ́lì ń bẹ lára rẹ, láti mọ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí Olúwa mi ọba bá sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, wọn yóò sì ka èmi àti Sólómónì sí ẹlẹ́ṣẹ̀ Bí ó sì ti ń bá ọba sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Nátanì wòlíì sì wọlé Wọ́n sì sọ fún ọba pé, Nátanì wòlíì wà níbí Ó sì lọ ṣíwájú ọba, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ Nátanì sì wí pé, Ǹjẹ́ ìwọ, Olúwa mi ọba, ti sọ pé Àdóníjà ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn rẹ àti pé òun ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ Ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ ní òní, ó sì ti rúbọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ màlúù, àti ẹran ọlọ́ràá àti àgùntàn Ó sì ti pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, Balógun àti Ábíátarì àlùfáà Ní sinsin yìí wọ́n ń jẹ wọ́n ń mu pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wí pé, Kí Àdóníjà ọba kí ó pẹ́! Ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́ rẹ, àti ṣádókù àlùfáà, àti Bẹ́náyà ọmọ Jéhóiádà, àti Sólómónì ìránṣẹ́ rẹ ni kò pè Ṣé nǹkan yìí ni Olúwa mi ọba ti ṣe láìjẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ mọ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ Nígbà náà ni Dáfídì ọba wí pé, Pe Bátíṣébà wọlé wá Ó sì wá ṣíwájú ọba, ó sì dúró níwájú rẹ̀ Ọba sì búrá pé, Dájúdájú bí Olúwa ti wà ẹni tí ó ti gbàmí kúrò nínú gbogbo wàhálà, Lónìí dandan ni èmi yóò gbé ohun tí mo ti fi Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún yọ pé Sólómónì ọmọ rẹ ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn mi, àti pé yóò jókòó lórí ìtẹ́ mi ní ipò mi Nígbà náà ni Bátíṣébà tẹriba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba pé, Kí Olúwa mi Dáfídì ọba kí ó pẹ́! Dáfídì ọba sì wí pé, Ẹ pe Sadókù àlùfáà wọlé fún mi àti Nátanì wòlíì àti Bẹ́náyà ọmọ Jéhóíádà Nígbà tí wọ́n wá ṣíwájú ọba, Ó sì wí fún wọn pé Ẹ mú àwọn ìránṣẹ́ Olúwa yín pẹ̀lú yín kí ẹ sì mú kí Sólómónì ọmọ mi kí ó gun ìbaka mi, kí ẹ sì mú-un sọ̀kalẹ̀ wá sí Gíhónì Níbẹ̀ ni Sádókù àlùfáà àti Nátanì wòlíì fi òróró yàn án ní ọba lórí Ísírẹ́lì Ẹ fọn fèrè, kí ẹ sì ké pé, Kí Sólómónì ọba kí ó pẹ́! Nígbà náà ni kí ẹ sì gòkè pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì wá, kí ó sì jókòó sórí ìtẹ́ mi, kí ó sì jọba ní ipò mi Èmi ti yàn án ní ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà Bénáyà ọmọ Jéhóíádà sì dá ọba lóhùn pé, Àmín! Kí Olúwa Ọlọ́run Olúwa mi ọba, kéde rẹ̀ bẹ́ẹ̀ Bí Olúwa ti wà pẹ̀lú Olúwa mi ọba, bẹ́ẹ̀ ni kí ó wà pẹ̀lú Sólómónì kí ó lè mú kí ìjọba rẹ̀ pẹ́ ju ìtẹ́ Olúwa mi Dáfídì Ọba lọ! Nígbà náà ni Sadókù àlùfáà, Nátanì wòlíì, Bénáyà ọmọ Jéhóiádà, àwọn ará Kérétì àti Pélétì sì sọ̀kalẹ̀ wá wọ́n sì gbé Sólómónì gun ìbaka Dáfídì ọba wá sí Gíhónì Sádókù àlùfáà sì mú ìwo òróró láti inú àgọ́, ó sì dà á sí Sólómónì lórí Nígbà náà ni wọ́n sì fọn fèrè, gbogbo àwọn ènìyàn sì ké pé, Kí Sólómónì ọba kí ó pẹ́! Gbogbo ènìyàn sì gòkè tọ̀ ọ́ lẹ́yìn wọ́n ń fọn ìpè, wọ́n sì ń yọ ayọ̀ ńlá, tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì fún ìró wọn Àdóníjà àti gbogbo awọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ ọ́ bí wọ́n ti ń jẹun tán, wọ́n ń gbọ́ ipè, Jóábù sì wí pé, Kí ní ìtumọ̀ gbogbo ariwo nínú ìlú yìí Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Jónátanì ọmọ Ábíátarì àlùfáà sì dé, Àdóníjà sì wí pé, Wọlé wá, ọkùnrin yíyẹ ìwọ gbọ́dọ̀ mú ìròyìn rere wá Jónátanì sì dá a lóhùn pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá, Olúwa wa Dáfídì ọba ti fi Sólómónì jọba Ọba sì ti rán Sádókù àlùfáà, Nátanì wòlíì, Bénáyà ọmọ Jéhóíádà àti àwọn ará Kérétì àti Pélétì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ti gbé e gun ìbaka ọba, Sádókù àlùfáà àti Nátanì wòlíì ti fi òróró yàn án ní ọba ní Gíhónì Lati ibẹ̀ ni wọ́n ti gòkè wá pẹ̀lú ayọ̀, ìlú sì ń hó pẹ̀lú rẹ̀ Èyí ni ariwo tí ẹ̀yin ń gbọ́ Sólómónì sì ti jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì ti tún wá láti bá Olúwa wa Dáfídì Ọba yọ̀, wí pé, Kí Ọlọ́run rẹ̀ mú orúkọ Sólómónì lókìkí ju tirẹ̀ lọ àti kí ìtẹ́ rẹ̀ kí ó pọ̀ ju tirẹ̀ lọ! Ọba sì tẹ ara rẹ̀ ba lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì wí pé, Ògo ni fún Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó ti jẹ́ kí ojú mi rí ẹnìkan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ mi lónìí   Nígbà náà ni gbogbo àwọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ Àdóníjà dìde ní ìdágìrì, wọ́n sì túká Ṣùgbọ́n Àdóníjà sì bẹ̀rù Sólómónì, ó lọ, ó sì di ìwo pẹpẹ mú Nígbà náà ni a sì sọ fún Sólómónì pé, Adóníjà bẹ̀rù Sólómónì Ọba, ó sì di ìwo pẹpẹ mú, Ó wí pé, Jẹ́ kí ọba Sólómónì búra fún mi lónìí pé, òun kì yóò fi idà pa ìránṣẹ́ rẹ̀   Sólómónì sì dáhùn pé, Bí ó bá fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ ẹni ọ̀wọ̀, irun orí rẹ̀ kan kì yóò sì bọ́ sílẹ̀ ṣùgbọ́n bí a bá rí búburú kan ní ọwọ́ rẹ̀ òun yóò kú Nígbà náà ni Sólómónì ọba rán àwọn ènìyàn, wọ́n sì mú un sọ̀kalẹ̀ láti ibi pẹpẹ wá Àdóníjà sì wá, ó sì foríbalẹ̀ fún Sólómónì ọba, Sólómónì sì wí pé, Lọ ilé rẹ Ayaba Ṣébà Bẹ Sólómónì Wò Nígbà tí ayaba Ṣébà gbọ́ òkìkí Sólómónì àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ níti orúkọ Olúwa , ó sì wá láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè líle Ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ràkúnmí tí ó ru tùràrí, ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Sólómónì, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀ Sólómónì sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀ kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un Nígbà tí ayaba Ṣébà sì rí gbogbo ọgbọ́n Sólómónì àti ààfin tí ó ti kọ́ Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ ọrẹ̀ sísun tí ó sun ní ilé Olúwa , kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́! Ó sì wí fún ọba pé, Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní orílẹ̀ èdè mi níti iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ Ṣùgbọ́n èmi kò sì gba nǹkan wọ̀nyí gbọ́ títí ìgbà tí mo wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i Sì kíyèsí i, a kò sọ ìdajì wọn fún mi ìwọ sì ti fi ọgbọ́n àti ìrora kọjá òkìkí tí mo gbọ́ Báwo ni inú àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe dùn tó! Báwo ni inú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọgbọ́n rẹ! Ìbùkún ni fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ní inú dídùn sí ọ, tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ Ísírẹ́lì Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn Ísírẹ́lì títí láé, ni ó ṣe fi ọ́ jọba, láti ṣe ìdájọ́ àti òdodo Ó sì fún ọba ní ọgọ́fà talẹ́ńtì wúrà, tùràrí olóòórún dídùn lọ́pọ̀lọpọ̀, àti òkúta iyebíye Kò sí irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tùràrí tí a mú wá tí ó dà bí irú èyí tí ayaba Ṣébà fi fún Sólómónì ọba Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọkọ̀ Hírámù tí ó mú wúrà láti ófírì wá wọ́n mú igi Álúgúmù, ógì Sáńdálì lọ́pọ̀lọpọ̀ àti òkúta oníyebíye láti ófírì wá Ọba sì fi igi Álúgúmù náà ṣe òpó fún ilé Olúwa àti fún ààfin ọba, àti láti ṣe dùùrù pẹ̀lú àti ohun èlò orin mìíràn fún àwọn akọrin Irú igi Álúgúmù bẹ́ẹ̀ kò dé mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí wọn títí di òní yìí Sólómónì ọba sì fún ayaba Ṣébà ní gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ àti ohun tí ó béèrè, yàtọ̀ sí èyí tí a fi fún un láti ọwọ́ Sólómónì ọba wa Nígbà náà ni ó yípadà, ó sì lọ sí ìlú rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ Ìwọ̀n wúrà tí Sólómónì ń gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà talẹ́ńtì wúrà, Láìka èyí tí ó ń gbà lọ́wọ́ àwọn ajẹ́lẹ̀ àti àwọn oníṣòwò, àti ti gbogbo àwọn ọba Árábíà, àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀ Sólómónì ọba sì ṣe igba aṣà wúrà lílù ẹgbẹ̀ta ṣékélì wúrà ni ó lọ sí asà kan Ó sì tún ṣe ọ̀ọ́dúrún aṣà wúrà lílù, pẹ̀lú òṣùwọ̀n wúrà mẹ́ta tí ó tàn sí aṣà kọ̀ọ̀kan Ọba sì kó wọn sí ilé igbó Lébánónì Nígbà náà ni ọba sì ṣe ìtẹ́ èyín erin ńlá kan, ó sì fi wúrà dídára bò ó Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, èyín rẹ̀ sì ṣe róbótó lókè Ní ibi ìjókòó méjèèjì náà ni irọpá wà, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìkọ̀ọ̀kan wọn Kìnnìún méjìlá sì dúró níbi àtẹ̀gùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ọ̀kọ̀kan ní òpin àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, kò tí ì sí irú rẹ̀ ní ìjọba kan rí Gbogbo ohun èlò mímu Sólómónì ọba sì jẹ́ wúrà àti gbogbo ohun èlò ààfin igbó Lébánónì sì jẹ́ kìkì wúrà Kò sí ìkankan tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkankan ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì Ọba sì ní ọkọ̀ Tásísì kan pẹ̀lú ọkọ̀ Hírámù ní òkun Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ọkọ̀ Tásísì ń dé, tí ó ń mú wúrà àti fàdákà, eyín-erin àti ìnàkí àti ẹyẹ-ológe wá Sólómónì ọba sì pọ̀ ní ọrọ̀ àti ní ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba ayé lọ Gbogbo ayé sì ń wá ojú Sólómónì láti gbọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sí i ní ọkàn Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún olúkúlùkù àwọn tí ń wá sì ń mú ẹ̀bùn tirẹ̀ wá, ohun èlò fàdákà àti ohun èlò wúrà àti ẹ̀wù, àti tùràrí olóòórùn dídùn, ẹṣin àti ìbááka Sólómónì sì kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ ó sì ní egbèje kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàata ẹlẹ́ṣin, tí ó fi pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù Ọba sì jẹ́ kí fàdákà pọ̀ ní Jérúsálẹ́mù bí òkúta, àti igi kédárì ni ó ṣe kí ó dàbí igi síkámórè tí ń bẹ ní àfonífojì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ A sì mú ẹṣin wá fún Sólómónì láti Éjíbítì ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, oníṣòwò ọba ni ó ń mú wọn wá fún òwe Wọ́n ń mú kẹ̀kẹ́ kan gòkè láti Éjíbítì wá fún ẹgbẹ̀ta ṣékélì fàdákà àti ẹsin kan fún àádọ́jọ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún mú wọn wá fún ọba àwọn ọmọ Hítì àti ọba àwọn ọmọ Árámánì Àwọn Ìyàwó Sólómónì Sólómónì ọba fẹ́ ọ̀pọ̀ àjèjì obìnrin yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Fáráò, àwọn ọmọbìnrin Móábù, àti ti Ámónì, ti Édómù, ti Sídónì àti ti àwọn ọmọ Hítì Wọ́n wá láti orílẹ̀ èdè tí Olúwa ti wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fẹ́ wọn níyàwó tàbí ní ọkọ, nítorí wọn yóò yí ọkàn yín padà sí òrìṣà wọn Síbẹ̀ síbẹ̀ Sólómónì fà mọ́ wọn ní ìfẹ́ Ó sì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin obìnrin, àwọn ọmọ ọba àti ọ̀ọ́dúnrun àlè, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà Bí Sólómónì sì ti di arúgbó, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà sí ọlọ́run mìíràn, ọkàn rẹ̀ kò sì ṣe déédé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dáfídì bàbá rẹ̀ ti ṣe Ó tọ Ásítórétì òrìṣà àwọn ará Sídónì lẹ́yìn, àti Mílíkómì òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ámónì Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì ṣe búburú níwájú Olúwa kò sì tọ Olúwa lẹ́yìn ní pípé, bí Dáfídì bàbá rẹ̀ ti ṣe Lórí òkè tí ń bẹ níwájú Jérúsálẹ́mù, Sólómónì kọ́ ibi gíga kan fún Kémósì, òrìṣà ìríra Móábù, àti fún Mólékì, òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ámónì Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn àjèjì obìnrin rẹ̀, ẹni tí ń sun tùràrí, tí wọ́n sì ń rúbọ fún òrìṣà wọn Olúwa bínú sí Sólómónì nítorí ọkàn rẹ̀ ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó ti fi ara hàn án lẹ́ẹ̀méjì Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kìlọ̀ fún Sólómónì kí ó má ṣe tọ àwọn Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, ṣùgbọ́n Sólómónì kò pa àṣẹ Olúwa mọ́ Nítorí náà Olúwa wí fún Sólómónì pé, Nítorí bí ìwọ ti ṣe nǹkan yìí, tí ìwọ kò sì pa májẹ̀mú mi àti àṣẹ mi mọ́, tí mo ti pa láṣẹ fún ọ, dájúdájú èmi yóò fa ìjọba ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, èmi yóò sì fi fún ẹlòmìíràn Ṣùgbọ́n, nítorí Dáfídì baba rẹ, Èmi kì yóò ṣe é ní ọjọ́ rẹ Èmi yóò fà á ya kúrò lọ́wọ́ ọmọ rẹ Síbẹ̀ èmi kì yóò fa gbogbo ìjọba náà ya, ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi, àti nítorí Jérúsálẹ́mù tí èmi ti yàn Nígbà náà ni Olúwa gbé ọ̀ta kan dìde sí Sólómónì, Hádádì ará Édómù ìdílé ọba ni ó ti wá ní Édómù Ó sì ṣe, nígbà tí Dáfídì wà ní Édómù, Jóábù olórí ogun sì gòkè lọ láti sìn àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ti a pa lójú ogun, ó sì pa gbogbo ọkùnrin Édómù Nítorí Jóábù àti gbogbo Ísírẹ́lì sì dúró níbẹ̀ fún oṣù mẹ́fà, títí wọ́n fi pa gbogbo ọkùnrin Édómù run Ṣùgbọ́n Hádádì sá lọ sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn ará Édómù tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ bàbá rẹ̀ Hádádì sì wà ní ọmọdé nígbà náà Wọ́n sì dìde kúrò ní Mídíánì, wọ́n sì lọ sí Páránì Nígbà náà ni wọ́n mú ènìyàn pẹ̀lú wọn láti Páránì wá, wọ́n sì lọ sí Éjíbítì, sọ́dọ̀ Fáráò ọba Éjíbítì ẹni tí ó fún Hádádì ní ilé àti ilẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ Inú Fáráò sì dùn sí Hádádì púpọ̀ tí ó fi fún un ní arábìnrin aya rẹ̀ ní aya, arábìnrin Tápénésì, ayaba Arábìnrin Tápénésì bí ọmọkùnrin kan fún un tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Génúbátì, ẹni tí Tápénésì tọ́ dàgbà ní ààfin ọba Níbẹ̀ ni Génúbátì ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Fáráò fún ra rẹ̀ Nígbà tí ó sì wà ní Éjíbítì, Hádádì sì gbọ́ pé Dáfídì ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àti pé Jóábù olórí ogun sì ti kú pẹ̀lú Nígbà náà ni Hádádì wí fún Fáráò pé, Jẹ́ kí n lọ, kí èmi kí ó le padà sí ìlú mi Fáráò sì wí fún un pé, Kí ni ìwọ ṣe aláìní níbí, tí ìwọ fi fẹ́ padà lọ sí ìlú rẹ Hádádì sì wí pé, Kò sí nǹkan, ṣùgbọ́n sá à jẹ́ kí èmi kí ó lọ! Ọlọ́run sì gbé ọ̀ta mìíràn dìde sí Sólómónì, Résónì ọmọ Élíádà, ẹni tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ Hádádésérì olúwa rẹ̀, ọba Sóbà Ó sì kó ènìyàn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí ogun ẹgbẹ́ kan, nígbà tí Dáfídì fi pa ogun Sóbà run wọ́n sì lọ sí Dámásíkù, wọ́n ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì jọba ní Dámásíkù Résónì sì jẹ́ ọ̀ta Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì, ó ń pa kún ibi ti Hádádì ṣe Bẹ́ẹ̀ ni Résónì jọba ní Síríà, ó sì sòdì sí Ísírẹ́lì Bákan náà Jéróbóámù ọmọ Nébátì sì sọ̀tẹ̀ sí ọba Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì, ará Éfúrátì ti Sérédà, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ opó, orúkọ rẹ̀ ni Sérúà Èyí sì ni ìdí tí ó fi sọ̀tẹ̀ sí ọba Sólómónì kọ́ Mílò, ó sì di ẹ̀yà ìlú Dáfídì baba rẹ̀ Jéróbóámù jẹ́ ọkùnrin alágbára, nígbà tí Sólómónì sì rí bí ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dáradára, ó fi í ṣe olórí iṣẹ́ ìrú ilé Jóṣẹ́fù Ó sì ṣe, ní àkókò náà Jéróbóámù ń jáde kúrò ní Jérúsálẹ́mù Wòlíì Áhíjà ti Ṣílò sì pàdé rẹ̀ lójú ọ̀nà, ó sì wọ agbádá túntún Àwọn méjèèjì nìkan ni ó sì ń bẹ ní oko, Áhíjà sì gbá agbádá túntún tí ó wọ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá Nígbà náà ni ó sọ fún Jéróbóámù pé, Mú ọ̀nà mẹ́wàá fún ara rẹ, nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé Wò ó, èmi yóò fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Sólómónì, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ Ṣùgbọ́n nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti nítorí Jérúsálẹ́mù, ìlú tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, òun yóò ní ẹ̀yà kan Èmi yóò ṣe èyí nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ti sin Ásítórétì òrìṣà àwọn ará Sídónì, Kémósì òrìṣà àwọn ará Móábù, àti Mííkámù òrìṣà àwọn ọmọ Ámónì, wọn kò sì rìn ní ọ̀nà mi, tàbí ṣe èyí tí ó dára lójú mi, tàbí pa àṣẹ àti òfin mi mọ́ bí Dáfídì bàbá Sólómónì ti ṣe  Ṣùgbọ́n èmi kì yóò gba gbogbo ìjọba náà lọ́wọ́ Sólómónì èmi ti mú un jẹ́ olórí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi, ẹni tí mo yàn, tí ó sì ti pa òfin mi àti àṣẹ mi mọ́ Èmi yóò gba ìjọba náà ní ọwọ́ ọmọ rẹ̀, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ̀wàá fún ọ Èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ kí Dáfídì ìránṣẹ́ mi lè máa ní ìmọ́lẹ̀ níwájú mi nígbà gbogbo ní Jérúsálẹ́mù, ìlú tí mo ti yàn láti fi orúkọ mi síbẹ̀ Ṣùgbọ́n ní ti ìwọ, Èmi yóò mú ọ, ìwọ yóò sì jọba lórí ohun gbogbo tí ọkàn rẹ ń fẹ́ ìwọ yóò jọba lórí Ísírẹ́lì Bí ìwọ bá ṣe gbogbo èyí tí mo pàṣẹ fún ọ, tí o sì rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú mi nípa pípa òfin àti àṣẹ mi mọ́, bí i Dáfídì ìránṣẹ́ mi ti ṣe, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ Èmi yóò kọ́ ilé òtítọ́ fún ọ bí èyí tí mo kọ́ fún Dáfídì, èmi yóò sì fi Ísírẹ́lì fún ọ Èmi yóò sì rẹ irú ọmọ Dáfídì sílẹ̀ nítorí èyí, ṣùgbọ́n kì í ṣe títí láé   Sólómónì wá ọ̀nà láti pa Jéróbóámù, ṣùgbọ́n Jéróbóámù sá lọ sí Éjíbítì, sọ́dọ̀ Ṣísákì ọba Éjíbítì, ó sì wà níbẹ̀ títí Sólómónì fi kú Ìyòókù iṣẹ́ Sólómónì àti gbogbo èyí tí ó ṣe, àti ọgbọ́n rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìṣe Sólómónì bí Sólómónì sì jọba ní Jérúsálẹ́mù lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní ogójì ọdún Nígbà náà ni ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì baba rẹ̀ Réhóbóámù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Ísírẹ́lì Ṣọ̀tẹ̀ Sí Réhóbóámù Réhóbóámù sì lọ sí Ṣékémù, nítorí gbogbo Ísírẹ́lì ti lọ síbẹ̀ láti fi í jẹ ọba Nígbà tí Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó wà ní Éjíbítì síbẹ̀ gbọ́, nítorí tí ó ti sá kúrò níwájú Sólómónì ọba, ó sì wà ní Éjíbítì Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jéróbóámù, òun àti gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì sì lọ sọ́dọ̀ Réhóbóámù, wọ́n sì wí fún un pé Baba rẹ sọ àjàgà wa di wúwo, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mú kí ìsìn baba rẹ̀ tí ó le, àti àjàgà rẹ̀ tí ó wúwo, tí ó fi sí wa ní ọrùn kí ó fẹ́rẹ̀ díẹ̀, àwa yóò sì sìn ọ́ Réhóbóámù sì wí fún wọn pé, Ẹ lọ ná títí di ọjọ́ mẹ́ta, nígbà náà ni kí ẹ padà tọ̀ mí wá Àwọn ènìyàn náà sì lọ Nígbà náà ni Réhóbóámù ọba fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbààgbà tí ń dúró níwájú Sólómónì baba rẹ̀ nígbà tí ó wà láàyè Ó sì béèrè pé, Ìmọ̀ràn wo ni ẹ̀yin yóò gbà mí láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn Wọ́n sì dá a lóhùn pé, Bí ìwọ yóò bá jẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí lónìí, kí o sì sìn wọ́n, àti kí o sì sọ ọ̀rọ̀ rere sí wọn nígbà tí ìwọ bá ń dá wọn lóhùn, wọn yóò má a ṣe ìránṣẹ́ rẹ títí láé Ṣùgbọ́n Réhóbóámù kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọmọdé tí wọ́n dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín Ó sì bi wọ́n pé, Kí ni ìmọ̀ràn yín Báwo ni a ó ṣe dá àwọn ènìyàn yí lóhùn, tí wọ́n wí fún mi pé, Ṣé kí àjàgà tí baba rẹ fi sí wa lọ́rùn kí ó fúyẹ́ díẹ̀ Àwọn ọmọdé tí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ dá a lóhùn pé, Sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wí fún ọ pé, Baba rẹ̀ mú kí àjàgà wa wúwo ṣùgbọ́n ìwọ mú kí ó fúyẹ́ díẹ̀ fún wa sọ fún wọn pé, ìka ọwọ́ mi kékeré nípọn ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ Baba mi ti gbé àjàgà wúwo lé e yín Èmi yóò sì fi kún àjàgà yín Baba mi ti fi pàsán nà yín Èmi yóò fi àkéekèe nà yín Jéróbóámù àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wá sọ́dọ̀ Réhóbóámù ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ọba ti wí pé, Ẹ padà tọ̀ mí wá ní ọjọ́ kẹta Ọba sì fi ohùn líle dá àwọn ènìyàn lóhùn, ó sì kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un, Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọmọdé, ó sì wí pé, Baba mí sọ àjàgà yín di wúwo Èmi yóò sì jẹ́ kí ó wúwo sí i Baba mi fi pàsán nà yín Èmi yóò fí àkéekèe nà yín Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fi etí sí ti àwọn ènìyàn, nítorí tí ọ̀ràn náà ti ọwọ́ Olúwa wá láti mú ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún Jéróbóámù ọmọ Nébátì láti ẹnu Áhíjà ará Ṣílò ṣẹ Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti àwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn pé ìpín wo ni àwa ní nínú Dáfídì, Ìní wo ni àwa ní nínú ọmọ Jésè Padà sí àgọ́ rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì! Bojútó ilé ara rẹ, ìwọ Dáfídì! Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Ísírẹ́lì padà sí ilé wọn Ṣùgbọ́n fún ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń gbé nínú ìlú Júdà, Réhóbóámù jọba lóri wọn síbẹ̀ Réhóbóámù ọba rán Ádórámù jáde, ẹni tí ń ṣe olórí iṣẹ́ irú, ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa, Réhóbóámù ọba, yára láti gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì sá lọ sí Jérúsálẹ́mù Bẹ́ẹ̀ ni Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dáfídì títí di òní yìí Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ pé Jéróbóámù ti padà dé, wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì pè é wá sí àjọ, wọ́n sì fi jẹ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì Kò sí ẹnìkan tí ó tọ ilé Dáfídì lẹ́yìn bí kò ṣe kìkì ẹ̀yà Júdà nìkan Nígbà tí Réhóbóámù sì dé sí Jérúsálẹ́mù, ó kó gbogbo ilé Júdà jọ, àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n ń ṣe ológun, láti bá ilé Ísírẹ́lì jà àti láti mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Réhóbóámù, ọmọ Sólómónì Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Sémáíàh ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé Sọ fún Réhóbóámù, ọmọ Sólómónì, ọba Júdà àti fún gbogbo ilé Júdà àti ti Bẹ́ńjámínì, àti fún àwọn ènìyàn tó kù wí pé, Báyìí ni Olúwa wí Ẹ má ṣe gòkè lọ láti bá àwọn arákùnrin yín jà, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì Ẹ padà, olúkúlùkù yín sí ilé rẹ̀, nítorí nǹkan yìí láti ọ̀dọ̀ mi wá ni   Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa , wọ́n sì tún padà sí ilé wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa Nígbà náà ni Jéróbóámù kọ́ Ṣékémù ní òkè Éfúráímù, ó sì ń gbé inú rẹ̀ Láti ibẹ̀ ó sì jáde lọ, ó sì kọ́ Pénúélì Jéróbóámù rò nínú ara rẹ̀ pé, Ìjọba náà yóò padà nísinsìnyìí sí ilé Dáfídì Bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá gòkè lọ láti ṣe ìrúbọ ní ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, wọn yóò tún fi ọkàn wọn fún Olúwa wọn, Réhóbóámù ọba Júdà Wọn yóò sì pa mí, wọn yóò sì tún padà tọ Réhóbóámù ọba Júdà lọ Lẹ́yìn tí ó ti gba ìmọ̀ràn, ọba sì yá ẹgbọ̀rọ̀ màlúù wúrà méjì Ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, Ó ti pọ̀jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù Àwọn Ọlọ́run yín nìyìí, Ísírẹ́lì, tí ó mú yín láti ilẹ̀ Éjíbítì wá Ó sì gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní Bétélì, àti èkejì ní Dánì Nǹkan yìí sì di ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn sì lọ títí dé Dánì láti sin èyí tí ó wà níbẹ̀ Jéróbóámù sì kọ́ ojúbọ sórí ibi gíga, ó sì yan àwọn àlùfáà láti inú àwọn ènìyàn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe inú àwọn ọmọ Léfì Ó sì dá àṣè sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹjọ gẹ́gẹ́ bí àṣè tí ó wà ní Júdà, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ Ó ṣe èyí ní Bétélì, ó rú ẹbọ sí àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe Ó sì fi àwọn àlùfáà sí ibi gíga tí ó ti ṣe sí Bétélì Ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹjọ, oṣù tí ó rò ní ọkàn ara rẹ̀, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí ó kọ́ ní Bétélì Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dá àsè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì gun orí pẹpẹ náà lọ láti rú ẹbọ Ènìyàn Ọlọ́run Kan Láti Júdà Sì kíyèsii, ènìyàn Ọlọ́run kan wá láti Júdà sí Bétélì nípa ọ̀rọ̀ Olúwa , bì Jéróbóámù sì ti dúró lẹ́bàá a pẹpẹ láti fi tùràrí jóná Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni Olúwa wí A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jòsíàh ní ilé Dáfídì Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga yìí tí ó ń mú ọrẹ wá síbẹ̀, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ   Ní ọjọ́ kan náà ènìyàn Ọlọ́run sì fún wọn ní àmì kan wí pé Èyí ni àmì tí Olúwa ti kéde kíyèsii, pẹpẹ náà yóò ya, eérú tí ń bẹ lórí rẹ̀ yóò sì dànù Nígbà tí Jéróbóámù ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run, tí ó kígbe sí pẹpẹ náà ní Bétélì, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde nínú pẹpẹ, ó sì wí pé, Ẹ mú un ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ tí ó nà sí i sì kákò, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le fà á padà mọ́ Lẹ́sẹ̀ kan náà, pẹpẹ ya, eérú náà sì dànù kúrò lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí àmì tí ènìyàn Ọlọ́run ti fi fún un nípa ọ̀rọ̀ Olúwa Nígbà náà ní ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, Bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì gbàdúrà fún mi kí ọwọ́ mi lè padà bọ̀ sípò Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa , ọwọ́ ọba sì padà bọ̀ sípò, ó sì padà sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀ Ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, Wá bá mi lọ ilé, kí o sì wá nǹkan jẹ, èmi yóò sì fi ẹ̀bùn fún ọ Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run náà dá ọba lóhùn pé, Bí ìwọ yóò bá tilẹ̀ fún mi ní ìdajì ìní rẹ, Èmi kì yóò lọ pẹ̀lú rẹ tàbí kí èmi jẹ oúnjẹ tàbí mu omi ní ibí yìí Nítorí a ti pa á láṣẹ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tàbí padà ní ọ̀nà náà tí o gbà wá   Bẹ́ẹ̀ ni ó gba ọ̀nà mìíràn, kò sì padà gba ọ̀nà tí ó gbà wá sí Bétélì Wòlíì àgbà kan wà tí ń gbé Bétélì, ẹni tí àwọn ọmọ rẹ̀ dé, tí ó sì ròyìn gbogbo ohun tí ènìyàn Ọlọ́run náà ti ṣe ní Béttélì ní ọjọ́ náà fún un Wọ́n sì tún sọ fún baba wọn ohun tí ó sọ fún ọba Baba wọn sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Ọ̀nà wo ni ó gbà Àwọn ọmọ rẹ̀ sì fi ọ̀nà tí ènìyàn Ọlọ́run láti Júdà gbà hàn án Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi Nígbà tí wọ́n sì ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un tán, ó sì gùn ún Ó sì tẹ̀lé ènìyàn Ọlọ́run náà lẹ́yìn Ó sì rí i tí ó jókòó lábẹ́ igi Óákù kan, ó sì wí fún un pé, Ǹjẹ́ ìwọ ni ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Júdà wá bí Ó sì dá a lóhùn pé, Èmi ni Nígbà náà ni wòlíì náà sì wí fún un pé, Bá mi lọlé, kí o sì jẹun Ènìyàn Ọlọ́run náà sì wí pé, Èmi kò le padà sẹ́yìn tàbí bá ọ lọ ilé, tàbí kí èmi kí ó jẹ oúnjẹ tàbí mu omi pẹ̀lú rẹ níhìn ín A ti sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa pé Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi níhìn-ín tàbí kí o padà lọ nípa ọ̀nà tí ìwọ bá wá   Wòlíì àgbà náà sì wí fún un pé, Wòlíì ni èmi náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìwọ Ańgẹ́lì sì sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa pé Mú un padà wá sí ilé rẹ, kí ó lè jẹ oúnjẹ àti kí ó lè mu omi   Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà sì padà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì jẹ oúnjẹ ó sì mu omi ní ilé rẹ̀ Bí wọ́n sì ti jókòó ti tábìlì, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ wòlíì tí ó mú un padà wá pé Ó sì kígbe sí ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Júdà wá wí pé, Báyìí ni Olúwa wí Ìwọ ti ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́, ìwọ kò sì pa àṣẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́ Ìwọ padà, ìwọ sì ti jẹ oúnjẹ, ìwọ sì ti mu omi níbi tí ó ti sọ fún ọ pé kí ìwọ kí ó má ṣe jẹ oúnjẹ tàbí mu omi Nítorí náà, a kì yóò sin òkú rẹ sínú ibojì àwọn baba rẹ   Nígbà tí ènìyàn Ọlọ́run sì ti jẹun tán àti mu omi tan, wòlíì tí ó ti mú u padà sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un Bí ó sì ti ń lọ ní ọ̀nà rẹ̀, kìnnìún kan pàdé rẹ̀ ní ọ̀nà, ó sì pa á, a sì gbé òkú rẹ̀ sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró tì í lẹ́gbẹ̀ẹ́ Àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá sì rí òkú náà, wọ́n sì lọ, wọ́n sì sọ ọ́ ní ìlú tí wòlíì àgbà náà ń gbé Nígbà tí wòlíì tí ó mú un padà wá láti ọ̀nà rẹ̀ sì gbọ́ èyí, ó sì wí pé, Ènìyàn Ọlọ́run náà ni tí ó ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́ Olúwa sì ti fi lé kìnnìún lọ́wọ́, tí ó sì fà á ya, tí ó sì pa á, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti kìlọ̀ fún un Wòlíì náà sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ Nígbà náà ni ó sì jáde lọ, ó sì rí òkú náà tí a gbé sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ Kìnnìún náà kò sì jẹ òkú náà, tàbí fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ya Nígbà náà ni wòlíì náà gbé òkú ènìyàn Ọlọ́run náà, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì gbé e padà wá sí ìlú ara rẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ fún un àti láti sin ín Nígbà náà ni ó gbé òkú náà sínú ibojì ara rẹ̀, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, wọ́n sì wí pé, Ó ṣe, arákùnrin mi! Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú rẹ̀ tán, ó sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, Nígbà tí mo bá kú, ẹ sin mí ní ibojì níbi tí a sin ènìyàn Ọlọ́run sí ẹ tẹ́ egungun mi lẹ́bàá egungun rẹ̀ Nítorí iṣẹ́ tí ó jẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Olúwa sí pẹpẹ tí ó wà ní Bétélì àti sí gbogbo ojúbọ lórí ibi gíga tí ń bẹ ní àwọn ìlú Samáríà yóò wá sí ìmúṣẹ dájúdájú Lẹ́yìn nǹkan yìí, Jéróbóámù kò padà kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún yan àwọn àlùfáà sí i fún àwọn ibi gíga nínú gbogbo àwọn ènìyàn Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di àlùfáà, a yà á sọ́tọ̀ fún ibi gíga wọ̀nyí Èyí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jéróbóámù, èyí tí ó yọrí sí ìṣubú rẹ̀, a sì pa á run kúrò lórí ilẹ̀ Áhíjà Sọtẹ́lẹ̀ Fún Jéróbóámù Ní àkókò náà Ábíjà ọmọ Jéróbóámù sì ṣàìsàn, Jéróbóámù sì wí fún aya rẹ̀ pé, Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́ ní aya Jéróbóámù Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣílò Áhíjà wòlíì wà níbẹ̀ ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jọba lórí àwọn ènìyàn yìí Mú ìṣù àkàrà mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, àti àkàrà wẹ́wẹ́ àti ìgò oyin, kí o sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ Òun yóò sì ṣọ fún ọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin náà Bẹ́ẹ̀ ni aya Jéróbóámù sì ṣe bí ó ti wí, ó sì lọ sí ilé Áhíjà ní Ṣílò Áhíjà kò sì ríran ojú rẹ̀ ti fọ́ nítorí ogbó rẹ̀ Ṣùgbọ́n Olúwa ti sọ fún Áhíjà pé, Kíyèsí i, aya Jéróbóámù ń bọ̀ wá béèrè nípa ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí ó ṣàìsàn, báyìí báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún un Nígbà tí ó bá dé, yóò ṣe ara rẹ̀ bí ẹlòmíràn Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, nígbà tí Áhíjà sì gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó sì wí pé, Wọlé wá, aya Jéróbóámù Kíló dé tí ìwọ fi ṣe ara rẹ bí ẹlòmíràn A ti fi iṣẹ́ búburú rán mi sí ọ Lọ, sọ fún Jéróbóámù pé báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Èmi sì gbé ọ ga láti inú àwọn ènìyàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórì lórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi Mo fa ìjọba náà ya kúrò ní ilé Dáfídì, mo sì fi fún ọ ṣùgbọ́n, iwọ kò dàbí Dáfídì ìránṣẹ́ mi, tí ó pa àṣẹ mi mọ́, tí ó sì tọ̀ mí lẹ́yìn tọkàntọkàn rẹ̀, láti ṣe kìkì èyí tí ó tọ́ ní ojú mi Ìwọ sì ti ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú rẹ lọ Ìwọ sì ti ṣe àwọn Ọlọ́run mìíràn fún ara rẹ, àwọn òrìṣà tí a gbẹ́ o sì ti mú mi bínú, o sì ti gbémi sọ sí ẹ̀yìn rẹ  Nítorí èyí, Èmi yóò mú ibi wá sí ilé Jéróbóámù Èmi yóò ké gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ Jéróbóámù, àti ọmọ ọ̀dọ̀ àti òmìnira ní Ísírẹ́lì Èmi yóò mú ilé Jéróbóámù kúrò bí ènìyàn ti ń kó ìgbẹ́ kúrò, títí gbogbo rẹ̀ yóò fi tán Ajá yóò jẹ ẹni Jéróbóámù tí ó bá kú ní ìlú, àti ẹni tí ó bá kú ní ìgbẹ́ ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ Olúwa ti sọ ọ́! Níti ìwọ, padà lọ ilé, nígbà tí o bá sì fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ ìlú, ọmọ náà yóò kú Gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì ṣọ̀fọ̀ fún un, wọn yóò sì sin ín Òun nìkan ni a ó sì sin nínú ẹni tí ń ṣe ti Jéróbóámù, nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ nìkan ni a ti rí ohun rere díẹ̀ sípa Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní ilé Jéróbóámù Olúwa yóò gbé ọba kan dìde fún ra rẹ̀ lórí Ísírẹ́lì tí yóò ké ilé Jéróbóámù kúrò Ọjọ́ náà nìyìí! Kí ni Àní nísinsìnyìí Olúwa yóò kọlu Ísírẹ́lì, yóò sì dà bí a ti ń mi ìyẹ́ nínú omi Yóò sì fa Ísírẹ́lì tu kúrò ní ilẹ̀ rere yìí, tí ó ti fi fún àwọn baba wọn, yóò sì fọ́n wọn ká kọjá odò, nítorí wọ́n ti rú ìbínú Olúwa nípa ṣíṣe ère òrìṣà Yóò sì kọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jéróbóámù ti ṣẹ̀ àti tí ó mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀ Nígbà náà ni aya Jéróbóámù sì dìde, ó sì lọ, ó sì lọ sí Tírà Bí ó sì ti fi ẹsẹ̀ tẹ ìloro ilé, ọmọdé náà sì kú Wọ́n sì sin ín, gbogbo Ísírẹ́lì sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí láti ẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀, Ábíjà wòlíì Ìyòókù ìṣe Jéróbóámù, bí ó ti jagun, àti bí ó ti jọba, ni a kọ sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì Jéróbóámù sì jọba fún ọdún méjìlélógún, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ Nádábù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Réhóbóámù ọmọ Sólómónì sì jọba ní Júdà Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, ó sì jọba ní ọdún mọ́kànlélógún ní Jérúsálẹ́mù, ìlú tí Olúwa ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀ Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Náámà, ará Ámónì Júdà sì ṣe búburú níwájú Olúwa nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọ́n ti dá, wọ́n sì mú u jowú ju gbogbo èyí tí baba wọn ti ṣe lọ Wọ́n sì tún kọ́ ibi gíga fún ara wọn, àti ère àti igbó òrìṣà lórí gbogbo òkè gíga, àti lábẹ́ gbogbo igi tútù Àwọn tí ń hùwà panṣágà sì tún ń bẹ ní ilẹ̀ náà, àwọn ènìyàn náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun ìríra àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa ti lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ó sì ṣe ní ọdún karùn ún Réhóbóámù, Sísákì ọba Éjíbítì kọlu Jérúsálẹ́mù Ó sì kó ìṣúra ilé Olúwa lọ àti ìṣúra ilé ọba Gbogbo rẹ̀ ni ó kó lọ, pẹ̀lú aṣà wúrà tí Sólómónì ti ṣe Réhóbóámù ọba sì ṣe asà idẹ ní ipò wọn, ó sì fi wọ́n sí ọwọ́ olórí àwọn olùṣọ́ tí ń sọ́ ilẹ̀kùn ilé ọba Nígbàkígbà tí ọba bá sì lọ sí ilé Olúwa Wọ́n á rù wọ́n, wọ́n á sì mú wọn padà sínú yàrá olùṣọ́ Níti ìyókù ìṣe Réhóbóámù, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà bí Ogun sì wà láàrin Réhóbóámù àti Jéróbóámù ní ọjọ́ wọn gbogbo Réhóbóámù sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní Ìlú Dáfídì Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Náámá ará Ámónì Ábíjà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Ábíjà Ọba Júdà Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jéróbóámù ọmọ Nébátì, Ábíjà jọba lórí Júdà, ó sì jọba ní ọdún mẹ́ta ní Jérúsálẹ́mù Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Máákà, ọmọbìnrin Ábúsálómù Ó sì rìn nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ti dá ṣáájú rẹ̀ ọkàn rẹ̀ kò sì pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dáfídì bàbáńlá rẹ̀ ti ṣe Ṣùgbọ́n, nítorí i Dáfídì Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fún un ní ìmọ́lẹ̀ kan ní Jérúsálẹ́mù nípa gbígbé ọmọ rẹ̀ ró láti jọba ní ipò rẹ̀ àti láti fi ìdí Jérúsálẹ́mù múlẹ̀ Nítorí tí Dáfídì ṣe èyí tí ó dára ní ojú Olúwa , tí kò sì kùnà láti pa gbogbo èyí tí Olúwa pa láṣẹ fún un mọ́ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo bí kò ṣe ní kìkì ọ̀ràn Ùráyà ará Hítì Ogun sì wà láàrin Réhóbóámù àti Jéróbóámù ní gbogbo ọjọ́ ayé Ábíjà Níti ìyókù ìṣe Ábíjà, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, a kò há kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà Ogun sì wà láàrin Ábíjà àti Jéróbóámù Ábíjà sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì Áṣà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Ní ogún ọdún Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Áṣà jọba lórí Júdà, Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù ní ọdún mọ́kànlélógójì Orúkọ ìyá ìyá rẹ̀ sì ni Máákà, ọmọbìnrin Ábúsálómù Áṣà sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa , bí Dáfídì baba rẹ̀ ti ṣe Ó sì mú àwọn tí ń ṣe panṣágà kúrò ní ilẹ̀ náà, ó sì kó gbogbo ère tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe kúrò Ó sì mú Máákà ìyá ìyá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún òrìṣà rẹ̀ Áṣà sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì dáná sun ún níbi odò Kídírónì Ṣùgbọ́n kò mú àwọn ibi gíga kúrò, síbẹ̀ ọkàn Áṣà pé pẹ̀lú Olúwa ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo Ó sì mú wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò tí òun àti bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wọ ilé Olúwa Ogun sì wà láàrin Áṣà àti Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn Bááṣà, ọba Ísírẹ́lì sì gòkè lọ sí Júdà, ó sì kọ́ Rámà láti má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde tàbí wọlé tọ Áṣà ọba lọ Nígbà náà ni Áṣà mú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó kù nínú ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ilé ọba Ó sì fi lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Bẹni-Hádádì ọmọ Tábírímónì, ọmọ Hésíónì ọba Síríà tí ó ń gbé ní Dámásíkù Ó sì wí pé, Jẹ́ kí májẹ̀mú kí ó wà láàrin èmi àti ìwọ, bí ó sì ti wà láàrin bàbá mi àti bàbá rẹ Wò ó, Èmi rán ọrẹ fàdákà àti wúrà sí ọ Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, da májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Bááṣà, ọba Ísírẹ́lì, kí ó lè lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Bẹni-Hádádì gba ti Áṣà ọba, ó sì rán àwọn alágbára olórí ogun rẹ̀ sí àwọn ìlú Ísírẹ́lì Ó sì ṣẹ́gun Íjónì, Dánì àti Abeli-Bẹti-Máákà, àti gbogbo Kénérótì pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Náfútalì Nígbà tí Bááṣà sì gbọ́ èyí, ó sì síwọ́ kíkọ́ Rámà, ó sì lọ kúrò sí Tírísà Nígbà náà ni Áṣà ọba kéde ká gbogbo Júdà, kò dá ẹnìkan sí wọ́n sì kó òkúta àti igi tí Bááṣà ń lò kúrò ní Rámà Áṣà ọba sì fi wọ́n kọ́ Gébà ti Bẹ́ńjámínì àti Mísípà Níti ìyókù gbogbo ìṣe Áṣà, àti gbogbo agbára rẹ̀, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti àwọn ìlú tí ó kọ́, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà Ṣùgbọ́n, ní ìgbà ogbó rẹ̀, àrùn ṣe é ní ẹṣẹ̀ rẹ̀ Áṣà sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀ ní ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀ Jèhóṣáfátì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Nádábù ọmọ Jéróbóámù sì jọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún kejì Áṣà ọba Júdà, ó sì jọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún méjì Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa , ó sì rìn ní ọ̀nà bàbá rẹ̀ àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó mú Ísírẹ́lì dá Bááṣà ọmọ Áhíjà ti ilé Ísákárì sì dìtẹ̀ sí i, Bááṣà sì kọlù ú ní Gíbétónì, ìlú àwọn ará Fílístínì, nígbà tí Nádábù àti gbogbo Ísírẹ́lì dó ti Gíbétónì Bááṣà sì pa Nádábù ní ọdún kẹta Áṣà ọba Júdà, ó sì jọba ní ipò rẹ̀ Ó sì ṣe, bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba ó pa gbogbo ilé Jéróbóámù, kò sì ku ẹnìkan tí ń mí fún Jéróbóámù, ṣùgbọ́n ó run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa , tí ó sọ nípa ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ Áhíjà ará Ṣílò Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jéróbóámù ti ṣẹ̀ àti tí ó mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀, àti nítorí tí ó ti mú Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú Níti ìyókù ìṣe Nádábù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì Ogun sì wà láàrin Áṣà àti Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ wọn Ní ọdún kẹta Áṣà ọba Júdà, Bááṣà ọmọ Áhíjà sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní Tírísà, ó sì jọba ní ọdún mẹ́rìnlélógún Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa , ó sì rìn ní ọ̀nà Jéróbóámù àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀ Élà Ọba Ísírẹ́lì Ó sì ṣe, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jéhù ọmọ Hánánì wá sí Bááṣà pé Èmi ti gbé ọ ga láti inú erùpẹ̀ wá, mo sì fi ọ́ ṣe olórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi, ṣùgbọ́n ìwọ sì rìn ní ọ̀nà Jéróbóámù, ó sì mú kí Ísírẹ́lì ènìyàn mi dẹ́ṣẹ̀, láti mú mi bínú nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn Nítorí náà, èmi yóò mú Bááṣà àti ile rẹ̀ kúrò, èmi yóò sì ṣe ilé rẹ̀ bí ilé Jéróbóámù ọmọ Nébátì Àwọn ajá yóò jẹ ẹni Bááṣà tí ó bá kú ní ìlú, ẹyẹ ojú ọ̀run yóò sì jẹ àwọn tí ó kú ní oko Àti ìyókù ìṣe Bááṣà, ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì Bááṣà sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní Tírísà Élà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Olúwa sì wá nípa ọwọ́ Jéhù wòlíì ọmọ Hánánì pẹ̀lú sí Bááṣà àti ilé rẹ̀, nítorí gbogbo búburú tí ó ti ṣe níwájú Olúwa , ní mímú un bínú nípa ohun tó ti ṣe àti wíwà bí ilé Jéróbóámù àti nítorí tí ó pa á run pẹ̀lú Ní ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n Áṣà ọba Júdà, Élà ọmọ Bááṣà bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba ní Ísírẹ́lì, ó sì jọba ní Tírísà ní ọdún méjì Ṣímírì, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, olórí ìdajì kẹ̀kẹ́ rẹ̀, dìtẹ̀ sí i Élà sì wà ní Tírísà nígbà náà, ó sì mu àmupara ní ilé Árísà, ìríjú ilé rẹ̀ ni Tírísà Ṣímírì sì wọlé, ó sì kọlù ú, ó sì pa á ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Áṣà, ọba Júdà, ó sì jọba ní ipò rẹ̀ Bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, bí ó sì ti jókòó lórí ìtẹ́, ó lu gbogbo ilé Bááṣà pa, kò ku ọkùnrin kan sílẹ̀, bóyá ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni Símírì pa gbogbo ilé Bááṣà run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ sí Bááṣà nípa ọwọ́ Jéhù wòlíì nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Bááṣà àti Élà ọmọ rẹ̀ ti ṣẹ̀ àti tí wọ́n ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀, tí wọ́n fi mú Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú, wọ́n mú u bínú nípa òrìṣà asán wọn Ìyòókù ìṣe Élà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Áṣà ọba Júdà, ni Ṣímírì jọba ọjọ́ méje ní Tírísà Àwọn ọmọ ogun sì dó ti Gíbétónì, ìlú àwọn ará Fílístínì Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó dó tì gbọ́ wí pé Símírì ti dìtẹ̀ sí ọba, ó sì ti pa á, wọ́n kéde Ómírì, olórí ogun, bí ọba lórí Ísírẹ́lì ní ọjọ́ náà ní ibùdó Nígbà náà ni Ómírì àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ kúrò ní Gíbétónì, wọ́n sì dó ti Tírísà Nígbà tí Ṣímírì sì ri pé a ti gba ìlú, ó sì wọ inú ààfin ilé ọba lọ, ó sì tẹ iná bọ ilé ọba lórí ara rẹ̀, ó sì kú, nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀, ní ṣíṣe búburú níwájú Olúwa àti ní rírìn ní ọ̀nà Jéróbóámù àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣe àti tí ó ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀ Níti ìyókù ìṣe Ṣímírì, àti ọ̀tẹ̀ rẹ̀ tí ó dì, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísiírẹ́lì Nígbà náà ní àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì dá sí méjì apákan wọn ń tọ Tíbínì ọmọ Gínátì lẹ́yìn, láti fi í jọba, apákan tókù sì ń tọ Ómírì lẹ́yìn Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí ń tọ Ómírì lẹ́yìn borí àwọn tí ń tọ Tíbínì ọmọ Gínátì lẹ́yìn Bẹ́ẹ̀ ni Tíbínì kú, Ómírì sì jọba Ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n Áṣà ọba Júdà, Ómírì bẹ̀rẹ̀ sí ń jọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì jọba ní ọdún méjìlá, ọdún mẹ́fà ní Tírisà Ó sì ra òkè Samáríà lọ́wọ́ Sérérì ní talẹ́ńtì méjì fàdákà, ó sì kọ́ ìlú sórí rẹ̀, ó sì pe ìlú náà ní Samáríà, nípa orúkọ Sémérì, orúkọ ẹni tí ó kọ́kọ́ ni òkè náà Ṣùgbọ́n Ómírì sì ṣe búburú níwájú Olúwa , Ó sì ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀ lọ Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà Jéróbóámù ọmọ Nébátì àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀, láti fi ohun asán wọn mú Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú Ìyòókù ìṣe àti ohun tí ó ṣe, àti agbára rẹ tí ó fi hàn, a kò ha kọ, wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì Ómírì sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín ní Ṣamáríà Áhábù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Ní ọdún kejìdínlógójì Áṣà ọba Júdà, Áhábù ọmọ Ómírì jọba ní Isireli, o si jọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà ní ọdún méjìlélógún Áhábù ọmọ Ómírì sì ṣe búburú ní ojú Olúwa ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀ lọ Ó sì ṣe bí ẹni pé ó ṣe ohun kékeré fún un láti máa rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, ó sì mú Jésébélì, ọmọbìnrin Étíbáálì, ọba àwọn ará Sídónì ní aya, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ń sin Báálì, ó sì bọ ọ́ Ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Báálì nínú ilé Báálì tí ó kọ́ sí Samáríà Áhábù sì tún ṣe ère òrìṣà kan, ó sì ṣe púpọ̀ láti mú Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú ju èyí tí gbogbo ọba Ísírẹ́lì tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ ti ṣe lọ Ní ìgbà ayé Áhábù, Híélì ará Bétélì kọ́ Jẹ́ríkò Ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀ ní Ábírámù, àkọ́bí rẹ, ó sì gbé àwọn ilẹ̀kùn ibodè rẹ̀ kọ́ ní Ṣégúdù àbíkẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti ipa Jóṣúà ọmọ Núnì sọ Àwọn Ẹyẹ Ìwò Bọ́ Èlíjà Èlíjà ará Tíṣíbì, láti Tíṣíbì ní Gílíádì wí fún Áhábù pé, Bí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, kì yóò sí ìrì tàbí òjò ní ọdún díẹ̀ tí ń bọ̀ bí kò ṣe nípa ọ̀rọ̀ mi Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Èlíjà wá pé kúrò níhìn ín, kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, kí o sì fi ara rẹ pamọ́ níbi odò Kérítì, tí ń bẹ níwájú Jọ́dánì Ìwọ yóò mu nínú odò náà, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò láti máa bọ́ ọ níbẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un Ó sì lọ sí ẹ̀bá odò Kérítì, tí ń bẹ níwájú Jọ́dánì, ó sì dúró síbẹ̀ Àwọn ẹyẹ ìwò sì mú àkàrà àti ẹran wá fún un ní òwúrọ̀, àti àkàrà àti ẹran ní alẹ́, ó sì ń mu nínú odò náà Ó sì ṣe lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, odò náà sì gbẹ nítorí kò sí òjò ní ilẹ̀ náà Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá wí pé Lọ nísinsìn yìí sí Ṣáréfátì ti Ṣídónì, kí o sì dúró síbẹ̀ Èmi ti pàṣẹ fún obìnrin opó kan níbẹ̀ láti máa bọ́ ọ Bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sí Ṣáréfátì Nígbà tí ó sì dé ibodè ìlú náà, obìnrin opó kan ń ṣa igi jọ níbẹ̀ Ó sì ké sí i, ó sì béèrè pé, Ǹjẹ́ o lè bu omi díẹ̀ fún mi wá nínú ohun èlò kí èmi kí ó lè mu Bí ó sì ti ń lọ bù ú wá, ó ké sí i pé, Jọ̀ ọ́, mú òkèlè oúnjẹ díẹ̀ fún mi wá lọ́wọ́ rẹ Obìnrin opó náà sì dá a lóhùn wí pé, Bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti wà, èmi kò ní àkàrà bí kò ṣe ìkúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú kólòbó Èmi ń ṣa igi díẹ̀ jọ láti kó lọ ilé, kí èmi kí ó sì pèsè rẹ̀ fún mi àti fún ọmọ mi, kí àwa lè jẹ ẹ́ kí a sì kú Èlíjà sì wí fún un pé, Má ṣe bẹ̀rù Lọ, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí Ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ṣe àkàrà kékeré kan fún mi nínú rẹ̀ ná, kí o sì mú fún mi wá, lẹ́yìn náà, kí o ṣe tìrẹ àti ti ọmọ rẹ Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Ìkòkò ìyẹ̀fun náà kì yóò ṣófo, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró náà kì yóò gbẹ, títí di ọjọ́ tí Olúwa yóò rọ òjò sí orí ilẹ̀   Ó sì lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Èlíjà ti sọ fún un Oúnjẹ sì wà fún Èlíjà àti obìnrin náà àti ilé rẹ̀ ní ojoojúmọ́ Nítorí ìkòkò ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, kólòbó òróró náà kò gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti ipa Èlíjà sọ Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọmọ obìnrin tí ó ni ilé náà ṣe àìsàn, àìsàn náà sì le tó bẹ́ẹ̀, tí ó fi kú Obìnrin náà sì wí fún Èlíjà pé, Kí lo ní sí mi, ènìyàn Ọlọ́run Ìwọ ha tọ̀ mí wá láti mú ẹ̀ṣẹ̀ mi wá sí ìrántí, àti láti pa mí ní ọmọ Èlíjà sì wí fún un pé, Gbé ọmọ rẹ fún mi Ó sì yọ ọ́ jáde ní àyà rẹ̀, ó sì gbé e lọ sí iyàrá òkè ilé níbi tí òun ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn tirẹ̀ Nígbà náà ni ó sì képe Olúwa wí pé, Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ ha mú ibi wá bá opó náà pẹ̀lú lọ́dọ̀ ẹni tí èmi ń ṣe àtìpó, nípa pípa ọmọ rẹ̀ Nígbà náà ni ó sì na ara rẹ̀ lórí ọmọdé náà ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta, ó sì képe Olúwa pé, Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọdé yìí kí ó tún padà tọ̀ ọ́ wá! Olúwa sì gbọ́ igbe Èlíjà, ẹ̀mí ọmọdé náà sì tún padà tọ̀ ọ́ wá, ó sì sọjí Èlíjà sì mú ọmọdé náà, ó sì gbé e sọ̀kalẹ̀ láti inú yàrá òkè náà wá sínú ilé Ó sì fi lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́ Èlíjà sì wí pé, Wò ó, ọmọ rẹ yè! Obìnrin náà sì wí fún Èlíjà pé, Nísinsìnyìí mo mọ̀ pé ènìyàn Ọlọ́run ni ìwọ ń ṣe, àti pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ẹnu rẹ Èlíjà àti Ọbadíà Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ní ọdún kẹta, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Èlíjà wá pé Lọ, kí o sì fi ara rẹ̀ hàn fún Áhábù, èmi yóò sì rọ òjò sórí ilẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni Èlíjà lọ fi ara rẹ̀ han Áhábù Ìyàn ńlá sì mú ní Samáríà, Áhábù sì ti pe Ọbadíàh, ẹni tí ń ṣe olórí ilé rẹ̀ Ọbadíà sì bẹ̀rù Olúwa gidigidi Nígbà tí Jésébélì sì ń pa àwọn wòlíì Olúwa kúrò, Ọbadíà sì mú ọgọ́rùn ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn Áhábù sì ti wí fún Ọbadíà pé, Lọ sí gbogbo ilẹ̀ sí orísun omi gbogbo àti sí ilẹ̀ gbogbo Bóyá àwa lè rí koríko láti gba àwọn ẹsin àti àwọn ìbááka là, kí a má báà ṣòfò àwọn ẹranko pátapáta Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pín ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ dé láàrin ara wọn, Áhábù gba ọ̀nà kan lọ, Ọbadíà sì gba ọ̀nà mìíràn lọ Bí Ọbadíà sì ti ń rìn lọ, Èlíjà sì pàdé rẹ̀ Ọbadíà sì mọ̀ ọ́, ó dojú bolẹ̀, ó sì wí pé, Ǹjẹ́ ìwọ ni ní tòótọ́, Èlíjà, Olúwa mi Èlíjà sì dá a lóhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni, lọ kí o sọ fún olúwa rẹ pé, Èlíjà ń bẹ níhìn ín   Ọbadíà sì béèrè pé, Ẹ̀ṣẹ̀ kí ni mo ha dá tí ìwọ fi ń fi ìránṣẹ́ rẹ lé Áhábù lọ́wọ́ láti pa Mo mọ̀ dájú pé bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ, kò sí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan tí olúwa mi kò ti rán ènìyàn lọ láti wò ọ́ Àti nígbà tí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan bá wí pé o kò sí, òun a sì mú kí wọ́n búra wí pé wọn kò rí ọ Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, ìwọ wí fún mi pé kí n lọ sọ́dọ̀ olúwa mi, kí n sì wí pé, Èlíjà ń bẹ níhìn ín Èmi kò sì mọ ibi tí ẹ̀mí Olúwa yóò gbé ọ lọ nígbà tí mo bá fi ọ́ sílẹ̀ Bí mo bá lọ, tí mo sì sọ fún Áhábù, tí kò sì rí ọ, òun a sì pa mí Ṣíbẹ̀ èmi ìránṣẹ́ rẹ bẹ̀rù Olúwa láti ìgbà èwe mi wá Ṣé Olúwa mi kò ha ti gbọ́ ohun tí mo ṣe nígbà tí Jésébélì ń pa àwọn wòlíì Olúwa Mo fi ọgọ́rùn ún wòlíì Olúwa pamọ́ sínú ihò òkúta méjì, àràádọ́ta ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo sì fi omi àti oúnjẹ bọ́ wọn Ìwọ sì sọ fún mi nísinsìn yìí pé, kí n tọ olúwa mi lọ pé, Èlíjà ń bẹ níhìn ín Òun a sì pa mí! Èlíjà sì wí pé, Bí Olúwa àwọn ọmọ ogun ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, ní tòótọ́ èmi yóò fi ara mi hàn fún Áhábù lónìí Bẹ́ẹ̀ ni Ọbadíà sì lọ láti pàdé Áhábù, ó sì sọ fún un, Áhábù sì lọ láti pàdé Èlíjà Nígbà tí ó sì rí Èlíjà, ó sì wí fún un pé, Ṣé ìwọ nìyìí, ìwọ tí ń yọ Ísírẹ́lì lẹ́nu Èlíjà sì dá a lóhùn pé, Èmi kò yọ Ísírẹ́lì lẹ́nu, bí kò ṣe ìwọ àti ilé bàbá rẹ Ẹ ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀, ẹ sì ń tọ Báálímù lẹ́yìn Nísinsìn yìí kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ láti pàdé mi lórí òkè Kámẹ́lì Àti kí o sì mú àádọ́tàlénírinwó àwọn wòlíì Báálì àti irinwó àwọn wòlíì ère òrìṣà tí wọ́n ń jẹun ní tábìlì Jésébélì Bẹ́ẹ̀ ni Áhábù ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì kó àwọn wòlíì jọ sí orí òkè Kámẹ́lì Èlíjà sì lọ ṣíwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin yóò máa ṣiyèméjì Bí Olúwa bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò sì wí ohun kan Nígbà náà ni Èlíjà wí fún wọn pé, Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù ní wòlíì Olúwa , ṣùgbọ́n, àádọ́tàlénírinwó ni wòlíì Báálì Ẹ fún wa ní ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù méjì Jẹ́ kí wọn kí ó sì yan ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan fún ara wọn, kí wọn kí ó sì ké e sí wẹ́wẹ́, kí wọn kí ó sì tò ó sí orí igi, kí wọn kí ó má ṣe fi iná sí i Èmi yóò sì tún ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kejì ṣe, èmi yóò sì tò ó sórí igi, èmi kì yóò sì fi iná sí i Nígbà náà ẹ ó sì képe orúkọ àwọn Ọlọ́run yín, èmi yóò sì képe orúkọ Olúwa Ọlọ́run náà tí ó fi iná dáhùn, òun ni Ọlọ́run Nígbà náà ni gbogbo àwọn ènìyàn náà sì wí pé, Ohun tí ìwọ sọ dára Èlíjà sì wí fún àwọn wòlíì Báálì wí pé, Ẹ yan ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan fún ara yín, kí ẹ sì tètè kọ́ ṣe é, nítorí ẹ̀yin pọ̀ Ẹ ké pe orúkọ àwọn Ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fi iná sí i Nígbà náà ni wọ́n sì mú ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù náà, tí a ti fi fún wọn, wọ́n sì ṣe é Nígbà náà ni wọ́n sì képe orúkọ Báálì láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán gangan wí pé, Báálì! Dáwa lóhùn! Wọ́n sì ń kégbe Ṣùgbọ́n kò sí ìdáhùn kò sí ẹnìkan tí ó sì dáhùn Wọ́n sì jó yí pẹpẹ náà ká, èyí tí wọ́n tẹ́ Ní ọ̀sán gangan, Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ó sì wí pé, Ẹ kígbe lóhùn rara Ọlọ́run ṣá à ni òun! Bóyá ó ń ṣe àṣàrò, tàbí kò ráyè, tàbí ó re àjò Bóyá ó sùn, ó yẹ kí a jí i Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kígbe lóhùn rara, wọ́n sì fi ọ̀bẹ àti ọ̀kọ̀ ya ara wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi tú jáde ní ara wọn Nígbà tí ọjọ́ yẹ àtàrí, wọ́n sì ń fi òmùgọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ohùn, kò sì sí ìdáhùn, kò sì sí ẹni tí ó kà á sí Nígbà náà ni Èlíjà wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, Ẹ súnmọ́ mi Wọ́n sì sún mọ́ ọn, ó sì tún pẹpẹ Olúwa tí ó ti wó lulẹ̀ ṣe Èlíjà sì mú òkúta méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà ọmọ Jákọ́bù kan, ẹni tí ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ wá wí pé, Ísírẹ́lì ni orúkọ rẹ̀ yóò máa jẹ́ Ó sì tẹ́ pẹpẹ pẹ̀lú àwọn òkúta wọ̀nyí ní orúkọ Olúwa , ó sì wa yàrá yí pẹpẹ náà ká, tí ó lè gba ìwọ̀n òṣùwọ̀n irúgbìn méjì Ó sì to igi náà dáradára, ó sì ké ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù náà wẹ́wẹ́, ó sì tò ó sórí igi Nígbà náà ni ó sì wí fún wọn wí pé, Ẹ fi omi kún ìkòkò mẹ́rin, kí ẹ sì tun sórí ẹbọ sísun àti sórí igi náà Ó sì wí pe, Ẹ ṣe é ní ìgbà kejì Wọ́n sì ṣe é ní ìgbà kejì Ó sì tún wí pé, Ṣe é ní ìgbà kẹta Omi náà sì ṣàn yí pẹpẹ náà ká, ó sì fi omi kún yàrà náà pẹ̀lú Ó sì ṣe, ní ìrúbọ àṣáálẹ́, wòlíì Èlíjà sì súnmọ́ tòsí, ó sì gbàdúrà wí pé, Olúwa , Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, jẹ́ kí ó di mímọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì àti pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa àṣẹ rẹ Gbọ́ ti èmi, Olúwa , gbọ́ ti èmi, kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lè mọ̀ pé ìwọ Olúwa ni Ọlọ́run àti pé ìwọ tún yí ọkàn wọn padà Nígbà náà ni iná Olúwa bọ́ sílẹ̀, ó sì sun ẹbọ síṣun náà àti igi, àti àwọn Òkúta, àti erùpẹ̀, ó sì tún lá omi tí ń bẹ nínú yàrà náà Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn sì rí èyí, wọ́n da ojú wọn bolẹ̀, wọ́n sì kígbe pé, Olúwa , òun ni Ọlọ́run! Olúwa , òun ni Ọlọ́run! Nígbà náà ni Èlíjà sì pàṣẹ fún wọn pé, Ẹ mú àwọn wòlíì Báálì Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀kan nínú wọn kí ó sá lọ! Wọ́n sì mú wọn, Èlíjà sì mú wọn sọ̀kalẹ̀ sí odò Kíṣónì, ó sì pa wọ́n níbẹ̀ Èlíjà sì wí fún Áhábù pé, Lọ, jẹ, kí o sì mu, nítorí ìró ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò ń bọ̀ Bẹ́ẹ̀ ni Áhábù gòkè lọ láti jẹ àti láti mu Ṣùgbọ́n Èlíjà gun orí òkè Kámẹ́lì lọ ó sì tẹríba, ó sì fi ojú rẹ̀ sí agbede-méjì eékún rẹ̀ Ó sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Lọ, kí o sì wo ìhà òkun, òun sì gòkè lọ, ó sì wò Ó sì wí pé, Kò sí nǹkan níbẹ̀ Ó sì wí pé, Tún lọ nígbà méje Nígbà keje, ìránṣẹ́ náà sì wí pé, Àwọ̀sánmọ̀ kékeré kan dìde láti inú òkun, gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ènìyàn Èlíjà sì wí pé, Lọ, kí o sọ fún Áhábù pé, Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ, kí òjò ó má ba à dá ọ dúró   Ó sì ṣe, nígbà díẹ̀ sí i, ọ̀run sì sú fún àwọsánmọ̀, ìjì sì dìde, òjò púpọ̀ sì rọ̀, Áhábù sì gun kẹ̀kẹ́ lọ sí Jésírẹ́lì Agbára Olúwa sì ń bẹ lára Èlíjà ó sì di àmùrè ẹ̀gbẹ́ rẹ, ó sì ṣáré níwájú Áhábù títí dé Jésírẹ́lì Èlíjà Sá Lọ Sí Hórébù Áhábù sì sọ gbogbo ohun tí Èlíjà ti ṣe fún Jésébélì àti bí ó ti fi idà pa gbogbo àwọn wòlíì Nítorí náà Jésébélì rán oníṣẹ́ kan sí Èlíjà wí pé, Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí èmi kò bá ṣe ẹ̀mí rẹ bí ọ̀kan nínú wọn ní ìwòyí ọ̀la Èlíjà sì bẹ̀rù, ó sá fún ẹ̀mí rẹ̀ Nígbà tí ó sì dé Bíáṣébà ti Júdà, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀, nígbà tí òun tìkárarẹ̀ sì lọ ní ìrìn ojọ́ kan sí ihà, ó sì wá sí ibi igi ọwọ̀ kan, ó sì jókòó lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbàdúrà kí òun bá le kú, wí pé, Mo ti ní tó, Olúwa , gba ẹ̀mí mi kúrò nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba mi lọ Nígbà náà ni ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi, ó sì sùn lọ Sì wòó, ańgẹ́lì fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, Dìdé, kí o jẹun Ó sì wò ó yíká, àkàrà tí a dín lórí ẹ̀yínná, àti orù-omi wà lẹ́bá orí rẹ̀ Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì tún dùbúlẹ̀ Ańgẹ́lì Olúwa sì tún padà wá lẹ́ẹ̀kejì, ó sì tún fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, Dìde, kí ó jẹun, nítorí ìrìnàjò náà jìn fún ọ Ó si dide, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Hórébù, òkè Ọlọ́run Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀ Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Èlíjà wá wí pé, Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí, Èlíjà Ó sì dáhùn wí pé, Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kọ májẹ̀mu rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi láti gbà á kúrò báyìí Olúwa sì wí pé, Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú Olúwa , nítorí Olúwa fẹ́ ré kọjá Nígbà náà ni ìjì ńlá àti líle sì fa àwọn òkè ńlá ya, ó sì fọ́ àwọn àpáta túútúú níwájú Olúwa ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìjì náà Lẹ́yìn ìjì náà ni ìsẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìsẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà Lẹ́yìn ìsẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà ni iná wá, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú iná náà Àti lẹ́yìn iná náà ni ohùn kẹ́lẹ́ kékeré wá Nígbà tí Èlíjà sì gbọ́ ọ, ó sì fi agbádá rẹ̀ bo ojú rẹ̀, ó sì jáde lọ, ó dúró ní ẹnu ihò òkúta náà Nígbà náà ni ohùn kan tọ̀ ọ́ wá wí pé, Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín, Èlíjà Ó sì dáhùn pé, Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kọ májẹ̀mu rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń gbìyànjú láti pa èmi náà báyìí Olúwa sì wí fún un pé, Padà lọ sí ọ̀nà tí ìwọ ti wá, kí o sì lọ sí ihà Dámásíkù Nígbà tí ìwọ bá dé ibẹ̀, fi òróró yan Hásáélì ní ọba lórí Árámù Tún fi òróró yan Jéhù ọmọ Nímísì ní ọba lórí Ísírẹ́lì, àti kí o fi òróró yan Èlíṣà ọmọ Sáfátì, ará Ábélí-Méhólà ní wòlíì ní ipò rẹ Jéhù yóò pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Hásáélì, Èlíṣà yóò sì pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Jéhù Ṣíbẹ̀, Èmi ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin ènìyàn mọ́ fún ara mi ní Ísírẹ́lì, àní gbogbo eékún tí kò ì tíì kúnlẹ̀ fún òrìṣà Báálì, àti gbogbo ẹnu tí kò ì tí ì fi ẹnu kò ó ní ẹnu Bẹ́ẹ̀ ni Èlíjà lọ kúrò níbẹ̀, ó sì rí Èlíṣà ọmọ Sáfátì Ó ń fi àjàgà màlúù méjìlá tulẹ̀ níwájú rẹ̀, àti òun náà níwájú ìkéjìlá Èlíjà sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì da agbádá rẹ̀ bò ó Nígbà náà ni Èlíṣà sì fi àwọn màlúù sílẹ̀, ó sì ṣáré tọ Èlíjà lẹ́yìn Ó wí pé, Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí èmi lọ fi ẹnu ko baba àti ìyá mi ní ẹnu Nígbà náà ni èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Èlíjà sì dáhùn wí pé, Padà ṣẹ́yìn, kí ni mo fi ṣe ọ́ Èlíṣà sì fi í sílẹ̀, ó padà ṣẹ́yìn Ó sì mú àjàgà màlúù rẹ, ó sì pa wọ́n Ó sì fi ohun-èlò àwọn màlúù náà bọ́ ẹran wọn, ó sì fi fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì jẹ Nígbà náà ni ó sì dìde láti tọ Èlíjà lẹ́yìn, ó sì ṣe ìránṣẹ́ fún un Dáfídì Pàṣẹ Fún Sólómónì Nígbà tí ọjọ́ ikú Dáfídì súnmọ́ etílé, ó pàṣẹ fún Sólómónì ọmọ rẹ̀ Ó sì wí pé, Èmi ti fẹ́ lọ sí ọ̀nà gbogbo ayé, nítorí náà jẹ́ alágbára kí o sì fi ara rẹ hàn bí ọkùnrin, kí o sì wòye ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mósè, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, kí Olúwa kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsí ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì Ìwọ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Jóábù ọmọ Ṣérúyà ṣe sí mi àti ohun tí ó ṣe sí balógun méjì nínú àwọn ológun Ísírẹ́lì, sí Ábínérì ọmọ Nérì àti sí Ámásà ọmọ Jétérì Ó sì pa wọ́n, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ ní ìgbà àlàáfíà bí í ti ojú ogun ó sì fi ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àmùrè rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti sí ara Sálúbàtà rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹṣẹ̀ rẹ̀ Ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà-òkú ní àlàáfíà Ṣùgbọ́n fi inú rere hàn sí àwọn ọmọ Bárísíláì, ti Gílíádì, jẹ́ kí wọn wà lára àwọn tí ó ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀ Wọ́n dúró tì mí nígbà tí mo sá kúrò níwájú Ábúsálómù arákùnrin rẹ̀ Àti kí o rántí, Ṣíméhì ọmọ Gérà ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì tí Báhúrímù wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Máhánáímù Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jọ́dánì, mo fi Olúwa búra fún un pé Èmi kì yóò fi idà pa ọ́ Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, má ṣe kíyèsí í gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n ni ìwọ ṣe ìwọ yóò mọ ohun tí ìwọ yóò ṣe sí i Mú ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà-òkú pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ Nígbà náà ni Dáfídì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì Ó ti jọba lórí Ísírẹ́lì ní ogójì ọdún ọdún méje ni Hébúrónì àti ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n ní Jérúsálẹ́mù Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fi ìdí múlẹ̀ gidigidi Wàyìí, Àdóníjà ọmọ Hágítì tọ Bátíṣébà, ìyá Sólómónì wá Bátíṣébà sì bi í pé, Àlàáfíà ni o bá wa bí Ó sì dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni Nígbà náà ni ó sì fi kún un pé, Mo ní ohun kan láti sọ fún ọ Bátíṣébà sì wí pé, Má a wí Ó wí pé, Gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ti tèmi ni ìjọba náà Gbogbo Ísírẹ́lì ti wò mí bí ọba wọn Ṣùgbọ́n nǹkan yípadà, ìjọba náà sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin mi, nítorí ó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ Olúwa wá Nísinsìnyí mo ní ìbéèrè kan láti bi ọ́, má ṣe kọ̀ fún mí Ó wí pé, O lè wí Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ̀ṣíwájú pé, Mo bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ sọ fún Sólómónì ọba kí ó fún mi ní Ábíságì ará Súnémù ní aya Bátíṣébà sì dáhùn pé, Ó dára èmi yóò bá ọba sọ̀rọ̀ nítorí rẹ̀ Nígbà tí Bátíṣébà sì tọ Sólómónì ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Àdóníjà, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ Ó sì wí pé, Mo ní ìbéèrè kékeré kan láti béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún mi Ọba sì dáhùn wí pé, Béèrè, ìyá mi Èmi kì yóò kọ̀ ọ́ Nígbà náà ni ó wí pé, Jẹ́ kí a fi Ábíságì ará Ṣúnémù fún Àdóníjà arákùnrin rẹ ní aya Sólómónì ọba sì dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé, Èéṣe tí ìwọ fi béèrè Ábíságì ará Súnémù fún Àdóníjà! Ìwọ ìbá sì béèrè ìjọba fún un pẹ̀lú nítorí ẹ̀gbọ́n mi ni í ṣe, fún òun pàápàá àti fún Ábíátarì àlùfáà àti fun Jóábù ọmọ Sérúíà! Nígbà náà ni Sólómónì ọba fi Olúwa búra pé Kí Ọlọ́run ki ó jẹ mí níyà, àti jù bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí Àdóníjà kò bá ní fi ẹ̀mí rẹ̀ san ìbéèrè yìí! Àti nísinsìnyí, bí ó ti dájú pé Olúwa wà láàyè ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dáfídì àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Àdóníjà! Sólómónì ọba sì pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Jéhóíádà, ó sì kọlu Àdóníjà, ó sì kú Ọba sì wí fún Ábíátarì àlùfáà pé, Padà lọ sí pápá rẹ ni Ánátótì, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsìn yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa níwájú Dáfídì baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì yọ Ábíátarì kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà Olúwa , kí ó lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípa ilé Élì ní Ṣílò ṣẹ Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Jóábù, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Àdóníjà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Ábúsálómù, ó sì sá lọ sínú àgọ́ Olúwa , ó sì di ìwo pẹpẹ mú A sì sọ fún Sólómónì ọba pé Jóábù ti sá lọ sínú àgọ́ Olúwa àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ Nígbà náà ni Sólómónì pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Johóíadà pé, Lọ, kí o sì kọlù ú Bénáyà sì wọ inú àgọ́ Olúwa , ó sì wí fún Jóábù pé, Ọba sọ wí pé, Jáde wá Ṣùgbọ́n ó dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, Èmi yóò kú níhìn ín Bénáyà sì mú èsì fún ọba, Báyìí ni Jóábù ṣe dá mi lóhùn Ọba sì pàṣẹ fún Bénáyà pé, Ṣe bí ó ti wí Kọ lù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé bàbá mi, tí Jóábù ti ta sílẹ̀ Olúwa yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dáfídì bàbá mi kò sì mọ̀ àwọn méjèèjì ni Ábínérì ọmọ Nérì olórí ogun Ísírẹ́lì, àti Ámásà ọmọ Jétérì olórí ogun Júdà, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnrarẹ̀ lọ Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn wá sórí Jóábù àti sórí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé Ṣùgbọ́n sórí Dáfídì àti irú-ọmọ rẹ̀, sí ilé rẹ̀ àti sí ìtẹ́ rẹ̀, ni kí àlàáfíà Olúwa wà títí láé Bẹ́ẹ̀ ni Bénáyà ọmọ Jéhóíádà sì gòkè lọ, ó sì kọlu Jóábù, ó sì pa á, a sì sin ín ní ilẹ̀ ibojì ara rẹ̀ ní ihà Ọba sì fi Bénáyà ọmọ Jéhóíádà jẹ olórí ogun ní ipò Jóábù àti Sádókù àlùfáà ní ipò Ábíátarì Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ sí Ṣíméhì ó sì wí fún un pé, Kọ́ ilé fún ara rẹ ní Jérúsálẹ́mù, kí o sì máa gbé ibẹ̀, ṣùgbọ́n kí o má sì ṣe lọ sí ibòmíràn Ọjọ́ tí ìwọ bá jáde, tí o sì kọjá pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì, kí ìwọ kí ó mọ̀ dájúdájú pé ìwọ yóò kú ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wà lórí ara rẹ Ṣíméhì sì dá ọba lóhùn pé, Ohun tí ìwọ sọ dára Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe bí Olúwa mi ọba ti wí Ṣíméhì sì gbé ní Jérúsálẹ́mù fún ìgbà pípẹ́ Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Síméì méjì sì sá lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì ọmọ Máákà, ọba Gátì, a sì sọ fún Síméì pé, Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ méjì wà ní Gátì Fún ìdí èyí, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì ní Gátì láti wá àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni Síméì sì lọ, ó sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ láti Gátì Nígbà tí a sì sọ fún Sólómónì pé Síméì ti lọ láti Jérúsálẹ́mù sí Gátì, ó sì ti padà, Ọba pe Síméì lẹ́jọ́, ó wí fún un pé, Ǹjẹ́ èmi kò ti mú ọ búra ní ti Olúwa , èmi sì ti kìlọ̀ fún ọ pé, Ní ọjọ́ tí ìwọ bá kúrò láti lọ sí ibikíbi, kí o mọ̀ dájú pé ìwọ yóò kú Nígbà náà ni ìwọ sì sọ fún mi pé, Ohun tí ìwọ sọ dára Èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn Èéṣe nígbà náà tí ìwọ kò pa ìbúra Olúwa mọ́, àti kí o sì ṣe ìgbọ́ràn sí àṣẹ tí mo pa fún ọ Ọba sì tún wí fún Síméì pé, Ìwọ mọ̀ ní ọkàn rẹ gbogbo búburú tí ìwọ ti ṣe sí Dáfídì baba mi Báyìí, Olúwa yóò san gbogbo ìṣe búburú rẹ padà fún ọ Ṣùgbọ́n a ó sì bùkún fún Sólómónì ọba, ìtẹ́ Dáfídì yóò sì wà láìfòyà níwájú Olúwa títí láéláé Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Jéhóíádà, ó sì jáde lọ, ó sì kọlu Ṣíméhì, ó sì pa á Ìjọba náà sì wá fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ Sólómónì Bẹni-Hádádì Kọlu Sámáríà Bẹni-Hádádì ọba Árámù sì gbá gbogbo ogun rẹ̀ jọ Ọba méjìlélọ́gbọ̀n sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ àti ẹsin àti kẹ̀kẹ́, ó sì gòkè lọ, ó sì dóti Samáríà, ó sì kọlù ú Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Áhábù ọba Ísírẹ́lì wí pé, Báyìí ni Bẹni-Hádádì wí Sílífà àti wúrà rẹ tèmi ni, àti àwọn tí ó dára jùlọ nínú àwọn aya re àti àwọn ọmọ rẹ tèmi ni wọ́n Ọba Ísírẹ́lì sì dá a lóhùn pé, Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ṣe wí Olúwa mi ọba, èmi àti ohun gbogbo tí mo ní tìrẹ̀ ni Àwọn ońṣẹ́ náà sì tún padà wá, wọ́n sì wí pé, Báyìí ni Bẹni-Hádádì sọ wí pé Mo ránṣẹ́ láti béèrè fún fàdákà rẹ àti wúrà rẹ, àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ Ṣùgbọ́n ní ìwòyí ọ̀la Èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ láti wá ilé rẹ wò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ Wọn yóò gba gbogbo ohun tí ó bá dára lójú rẹ, wọn yóò sì kó o lọ   Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì pe gbogbo àwọn àgbà ìlú, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ti ń fẹ́ ìyọnu! Nígbà tí ó ránṣẹ́ fún àwọn aya mi, àti fún àwọn ọmọ mi, àti fún fàdákà mi, àti fún wúrà mi, èmi kò sì fi dù ú Àwọn àgbà àti gbogbo ènìyàn dá a lóhùn pé, Má se fi etí sí tirẹ̀ tàbí kí o gbà fún un Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Bẹni-Hádádì pé, Sọ fún Olúwa mi ọba pé, Ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe ohun gbogbo tí ó ránṣẹ́ fún látètèkọ́ṣe, ṣùgbọ́n nǹkan yìí ni èmi kò le ṣe   Wọ́n padà lọ, wọ́n sì mú èsì padà wá fún Bẹni-hádádì Bẹni-Hádádì sì tún rán oníṣẹ́ mìíràn sí Áhábù wí pé, kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí eekuru Samáríà yóò tó fún ìkúnwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ń tẹ̀lé mi Ọba Ísírẹ́lì sì dáhùn wí pé, Sọ fún un pé Má jẹ́ kí ẹni tí ń hámọ́rà halẹ̀ bí ẹni tí ń bọ́ ọ sílẹ̀   Bẹni-Hádádì sì gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nigbà tí òun àti àwọn ọba ń mu ọtí nínú àgọ́ wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, Ẹ tẹgun sí ìlú náà Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe tan láti kọlu ìlú náà Sì kíyèsí i, wòlíì kan tọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì wá, ó sì wí pé, Báyìí ni Olúwa wí Ìwọ rí gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun yìí Èmi yóò fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ lónìí, nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa   Áhábù sì béèrè pé, Ṣùgbọ́n ta ni yóò ṣe èyí Wòlíì náà sì dáhùn wí pé, Ìwọ ni yóò ṣe é Nígbà náà ni Áhábù ka àwọn ìjòyè kéékèèkéé ìgbéríko, wọ́n sì jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n Nígbà náà ni ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù jọ, gbogbo wọn sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin Wọ́n sì jáde lọ ní ọ̀sán gangan, nígbà tí Bẹni-Hádádì àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n tí ń ràn án lọ́wọ́ ń mu àmúpara nínú àgọ́ Àwọn ìjòyè kékèké ìgbéríko tètè kọ́ jáde lọ Bẹni-Hádádì sì ránṣẹ́ jáde, wọ́n sì sọ fún un wí pé, Àwọn ọkùnrin ń ti Samáríà jáde wá Ó sì wí pé, Bí wọ́n bá bá ti àlàáfíà jáde wá, ẹ mú wọn láàyè bí ti ogun ni wọ́n bá bá jáde, ẹ mú wọn láàyè Àwọn ìjòyè kékèké wọ̀nyí ti àwọn ìjòyè ìgbéríko jáde ti ìlú wá, àti ogun tí ó tẹ̀lé wọn Olúkúlùkù sì pa ọkùnrin kọ̀ọ̀kan Àwọn ará Árámù sì sá, Ísírẹ́lì sì lépa wọn Ṣùgbọ́n Bẹni-Hádádì ọba Árámù sì sálà lórí ẹsin pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sin Ọba Ísírẹ́lì sì jáde lọ, ó sì kọlu àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́, ó pa àwọn ará Árámù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ Lẹ́yìn náà, wòlíì náà sì wá sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì, ó sì wí pé, Lọ, mú ara rẹ gírí, kí o sì mọ̀, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe, nítorí ní àmọ́dún ọba Árámù yóò tún gòkè tọ̀ ọ́ wá Àwọn ìránṣẹ́ ọba Árámù sì wí fún un pé, Ọlọ́run wọn, Ọlọ́run òkè ni Ìdí nìyìí tí wọ́n ṣe ní agbára jù wá lọ Ṣùgbọ́n bí a bá bá wọn jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ dájúdájú Nǹkan yìí ni kí o sì ṣe Mú àwọn ọba kúrò, olúkúlùkù kúrò ní ipò rẹ̀, kí o sì fi olórí ogun sí ipò wọn Kí o sì tún kó ogun jọ fún ara rẹ bí èyí tí ó ti sọnù ẹṣin fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ fún kẹ̀kẹ́ kí a bá lè bá Ísírẹ́lì jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Nítòótọ́ àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ Ó sì gba ti wọn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ Ó sì ṣe ní àmọ́dún, Bẹni-Hádádì ka iye àwọn ará Árámù, ó sì gòkè lọ sí Áfékì, láti bá Ísírẹ́lì jagun Nígbà tí a sì ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì pèsè oúnjẹ, wọ́n sì lọ pàdé wọn Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dó níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí agbo ọmọ ewúrẹ́ kékeré méjì, nígbà tí àwọn ará Árámù kún ilẹ̀ náà Ènìyàn Ọlọ́run kan sì gòkè wá, ó sì sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé, Báyìí ni Olúwa wí Nítorí tí àwọn ará Árámù rò pé Olúwa , Ọlọ́run òkè ni, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe Ọlọ́run àfonífojì, nítorí náà èmi ó fi gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí lé ọ lọ́wọ́, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa   Wọ́n sì dó ṣíwájú ara wọn fún ọjọ́ méje, àti ní ọjọ́ keje, wọ́n pàdé ogun Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì pa ọ̀kẹ́ márùn ún ẹlẹ́sẹ̀ nínú àwọn ará Árámù ní ọjọ́ kan Àwọn tókù sì sá àsálà lọ sí Áfékì, sínú ìlú tí odi ti wó lù ẹgbàámẹ́talá-lé ẹgbẹ̀rún nínú wọn Bẹni-Hádádì sì sá lọ sínú ìlú, ó sì fara pamọ́ sínú ìyẹ̀wù Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, Wò ó, a ti gbọ́ pé àwọn ọba ilẹ̀ Ísírẹ́lì jẹ́ ọba aláàánú, mo bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí àwa kí ó tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ wa, àti okùn yí orí wa ká Bóyá òun yóò gba ẹ̀mí rẹ là Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ wọn, Wọ́n sì fi okùn yí orí wọn ká, wọ́n sì tọ ọba Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì wí pé, Ìránṣẹ́ rẹ Bẹni-hádádì wí pé, Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́kí èmi kí ó yè   Ọba sì dáhùn wí pé, Ó ń bẹ láàyè bí Arákùnrin mi ni òun Àwọn ọkùnrin náà sì ṣe àkíyèsí gidigidi, wọ́n sì yára gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì wí pé, Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹni-Hádádì arákùnrin rẹ Ọba sì wí pé, Ẹ lọ mú u wá Nígbà tí Bẹni-Hádádì jáde tọ̀ ọ́ wá, Áhábù sì mú u gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́ Bẹni-Hádádì sì wí pé, Èmi yóò dá àwọn ìlú tí baba mi ti gbà lọ́wọ́ baba rẹ padà, ìwọ sì le la ọ̀nà fún ara rẹ ní Dámáskù, bí baba mi ti ṣe ní Samáríà Áhábù sì wí pé, Èmi yóò rán ọ lọ pẹ̀lú májẹ̀mú yìí Bẹ́ẹ̀ ni ó ba dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ Nípa ọ̀rọ̀ Olúwa , ọkùnrin kan nínú àwọn ọmọ àwọn wòlíì sì wí fún èkejì rẹ̀ pé, Jọ̀ ọ́, lù mí, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti lù ú Nígbà náà ni ó wí pé, Nítorí tí ìwọ kò gba ohùn Olúwa gbọ́, kíyèsí i, bí ìwọ bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, kìnnìún yóò pa ọ́ Bí ó ti jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kìnnìún kan rí i, ó sì pa á Wòlíì náà sì rí ọkùnrin mìíràn, ó sì wí fún un pé, Jọ̀ ọ́, lù mí Bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin náà sì lù ú, ó sì pa á lára Wòlíì náà sì lọ, ó sì dúró de ọba ní ojú ọ̀nà Ó pa ara rẹ̀ dà ní fífi eérú bo ojú Bí ọba sì ti ń ré kọjá, wòlíì náà ké sí i, ó sì wí pé, Ìránṣẹ́ rẹ jáde wọ àárin ogun lọ, ẹnìkan sì wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìgbékùn kan, ó sì wí pé, Pa ọkùnrin yìí mọ́ Bí a bá fẹ́ ẹ kù, ẹ̀mi rẹ yóò lọ dípò ẹ̀mí rẹ̀, tàbí kí ìwọ san talẹ́ǹtì fàdákà kan Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ìṣe níhìn ín àti lọ́hùn ún, a fẹ́ ẹ kù Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún un pé, Bẹ́ẹ̀ ni ìdájọ́ rẹ yóò rí, ìwọ fúnra rẹ ti dá a Nígbà náà ni wòlíì náà yára, ó sì mú eérú kúrò ní ojú rẹ̀, ọba Ísírẹ́lì sì mọ̀ ọ́ pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì ni ó ń ṣe Ó sì wí fún ọba pé, Báyìí ni Olúwa wí Ìwọ ti jọ̀wọ́ ọkùnrin tí èmi ti yàn sí ìparun pátapáta lọ́wọ́ lọ Nítorí náà, ẹ̀mí rẹ yóò lọ fún ẹ̀mí rẹ, ènìyàn rẹ fún ènìyàn rẹ̀   Ọba Ísírẹ́lì sì lọ sí ilé rẹ̀ ní wíwú gbọ, inú rẹ sì bàjẹ́, ó sì wá sí Samáríà Ọgbà Àjàrà Nábótì Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Nábótì ará Jésérẹ́lì sì ní ọgbà àjàrà kan ní Jésérẹ́lì, ní ẹ̀gbẹ́ ààfin Áhábù ọba Samáríà Áhábù sì wí fún Nábótì pé, Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ, kí èmi kí ó fi ṣe ọgbà-ewébẹ̀, nítorí tí ó súnmọ́ tòsí ilé mi Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó sàn jù ú lọ dípò rẹ̀ tàbí bí ó bá sì dára ní ojú rẹ, èmi yóò fi iye owó rẹ̀ fún ọ Ṣùgbọ́n Nábótì wí fún Áhábù pé, Olúwa má jẹ́ kí èmi fi ogún àwọn bàbá mi fún ọ Áhábù sì wá sí ilé rẹ̀, ó wugbọ́, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí Nábótì ará Jésérẹ́lì sọ fún un nítorí tí ó wí pé, Èmi kì yóò fún ọ ní ogún àwọn bàbá mi Ó sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì yí ojú rẹ̀ padà, kò sì fẹ́ jẹun Jésébélì aya rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Èéṣe tí inú rẹ fi bàjẹ́, Èéṣe tí ìwọ kò sì jẹun Ó sì dá a lóhùn pé, Nítorí tí mo wí fún Nábótì ará Jésérẹ́lì pé, Ta ọgbà àjàrà rẹ fún mi, tàbí bí ó bá wù ọ́, Èmi yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mìíràn ní ipò rẹ̀ Ṣùgbọ́n ó wí pé, Èmi kì yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mi   Jésébélì aya rẹ̀ sì wí pé, Ṣé báyìí ni ìwọ yóò ṣe ṣe bí ọba lórí Ísírẹ́lì Dìde, jẹun! Kí o sì jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésérẹ́lì Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ̀wé ní orúkọ Áhábù, ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì í, ó sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbààgbà àti àwọn ọlọ́lá tí ó ń gbé ní ìlú Nábótì pẹ̀lú rẹ̀ Nínú àwọn ìwé náà, ó kọ pé Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì fi Nábótì sí ipò ọlá láàrin àwọn ènìyàn Ṣùgbọ́n kí ẹ fi ènìyàn méjì, ẹni búburú ṣíwájú rẹ̀ láti jẹ́rìí pa á wí pé, ó bú Ọlọ́run àti ọba Nígbà náà ni kí ẹ mú u jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbààgbà àti àwọn ọlọ́lá tí wọ́n ń ṣe ará ìlú Nábótì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésébélì ti ránṣẹ́ sí wọn Wọ́n sì kéde ààwẹ̀, wọ́n sì fi Nábótì sí ipò ọlá láàrin àwọn ènìyàn Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin méjì sì dé, àwọn ẹni búburú, wọ́n sì jókòó ṣíwájú rẹ̀, wọ́n sì jẹ́rìí pa Nábótì níwájú àwọn ènìyàn wí pé, Nábótì ti bú Ọlọ́run àti ọba Nígbà náà ni wọ́n mú jáde kúrò ní ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa Nígbà náà ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jésébélì wí pé A ti sọ Nábótì ní òkúta, ó sì kú Bí Jésébélì sì ti gbọ́ pé, a ti sọ Nábótì ní Òkúta pa, ó sì wí fún Áhábù pé, Dìde! Kí o sì jogún ọgbà àjàrà Nábótì, ará Jésérẹ́lì, tí ó kọ̀ láti tà fún ọ kò sí láàyè mọ́, ó ti kú Nígbà tí Áhábù sì gbọ́ pé Nábótì ti kú, ó sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún ọgbà àjàrà Nábótì Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Èlíjà ará Tíṣíbì wá wí pé Sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ pàdé Áhábù ọba Ísírẹ́lì, tí ó wà ní Samáríà Ó wà ní ọgbà àjàrà Nábótì báyìí, níbi tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún rẹ̀ Sọ fún un pé, Báyìí ni Olúwa wí Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, Báyìí ni Olúwa wí Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ Nábótì, ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!  Áhábù sì wí fún Èlíjà pé, Ìwọ ti rí mi, ìwọ ọ̀ta mi! Ó sì dáhùn wí pé, Èmi ti rí ọ, nítorí tí ìwọ ti tan ara rẹ láti ṣe búburú níwájú Olúwa Èmi yóò mú ibi wá sórí rẹ Èmi yóò sì mú ìran rẹ kúrò, èmi yóò sì ké kúrò lọ́dọ̀ Áhábù gbogbo ọmọdé ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀, àti òmìnira ní Ísírẹ́lì Èmi yóò ṣe ilé rẹ bí ilé Jéróbóámù, ọmọ Nébátì, àti bí ilé Bááṣà, ọmọ Áhíjà, nítorí ìwọ ti mú mi bínú, ìwọ sì ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀ Àti níti Jésébélì pẹ̀lú Olúwa wí pé Àwọn ajá yóò jẹ Jésébélì nínú yàrá Jésírẹ́lì Àwọn ajá yóò jẹ ẹni Áhábù tí ó kú ní ìlú, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ àwọn ẹni tí ó kú ní ìgbẹ́ Nígbà tí Áhábù sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sí ara rẹ̀, ó sì gba ààwẹ̀ Ó sì dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì ń lọ jẹ́ ẹ́ Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Èlíjà ará Tíṣíbì wá wí pé Ǹjẹ́ ìwọ ti rí bí Áhábù ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi Nítorí tí ó ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀, èmi kì yóò mú ibi náà wá ní ọjọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò mú u wá sí ilé rẹ̀ ní ọjọ́ ọmọ rẹ̀ Míkáyà Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Áhábù Fún ọdún mẹ́ta kò sì sí ogun láàrin Árámù àti Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹ́ta, Jèhósáfátì ọba Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ láti rí ọba Ísírẹ́lì Ọba Ísírẹ́lì sì ti wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ti wa ni Ramoti Gílíádì, àwa sì dákẹ́ síbẹ̀, a kò sì gbà á padà lọ́wọ́ ọba Árámù Ó sì béèrè lọ́wọ́ Jèhósáfátì pé, Ṣé ìwọ yóò bá mi lọ láti lọ bá Ramoti-Gílíádì jà Jèhóṣáfátì sì dá ọba Ísírẹ́lì lóhùn pé, Èmi bí ìwọ, ènìyàn mi bí ènìyàn rẹ, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ Ṣùgbọ́n Jèhósáfátì sì tún wí fún ọba Ísírẹ́lì pé, Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Olúwa Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì jọ, bí irinwó ọkùnrin Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Ṣé kí n lọ sí Ramoti-Gílíádì lọ jagun, tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ̀ Wọ́n sì dáhùn pé, Lọ, nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́ Ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì béèrè pé, Ǹjẹ́ wòlíì Olúwa kan kò sí níhìn ín, tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ Ọba Ísírẹ́lì dá Jèhóṣáfátì lóhùn pé, Ọkùnrin kan sì wà, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa lè béèrè lọ́wọ́ Olúwa , ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀ nítorí kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kan nípa mi, bí kò ṣe ibi Míkáyà ọmọ Ímílà ni Jéhósáfátì sì wí pé, Kí ọba má ṣe sọ bẹ́ẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì sì pe ìránṣẹ́ kan, ó sì wí pé, Lọ yára mú Míkáyà, ọmọ Ímílà wá Ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà jókòó lórí ìtẹ́ wọn, wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà wọn ní ìta ẹnubodè Samáríà, gbogbo àwọn wòlíì náà sì ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn Ṣedekíà ọmọ Kénáánà sì ṣe ìwo irin fún ara rẹ̀, ó sì wí pé, Báyìí ni Olúwa wí Wọ̀nyí ni ìwọ yóò fi kan àwọn ará Árámù títí ìwọ yóò fi run wọ́n Gbogbo àwọn wòlíì tó kù sì ń sọtẹ́lẹ̀ ohun kan náà wí pé, Kọlu Ramoti-Gílíádì, kí o sì ṣẹ́gun Wọ́n sì wí pé, nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́ Ìránṣẹ́ tí ó lọ pe Míkáyà wí fún un pé, Wò ó, ẹnu kan náà ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì fi jẹ́ rere fún ọba Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ bá ti àwọn tókù mu, kí o sì sọ rere Ṣùgbọ́n Míkáyà wí pé, Bí Olúwa ti wà, ohun tí Olúwa bá sọ fún mi ni èmi yóò sọ fún un Nígbà tí ó sì dé, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Míkáyà, ṣé kí a lọ bá Ramoti-Gílíádì jagun, tàbí kí a jọ̀wọ́ rẹ̀ Ó sì dáhùn wí pé, Lọ, kí o sì ṣẹ́gun, nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́ Ọba sì wí fún un pé, Ìgbà mélòó ni èmi yóò fi ọ bú pé kí o má ṣe sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe òtítọ́ ní orúkọ Olúwa Míkáyà sì dáhùn pé, Mo rí gbogbo Ísírẹ́lì túkáàkiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, Olúwa sì wí pé, Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà   Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún Jèhósáfátì pé, Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún ọ pé kò fọ ire kan sí mi rí bí kò ṣe ibi Míkáyà sì tún wí pé, Nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Mo rí Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ogun ọ̀run dúró ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì rẹ̀ Olúwa sì wí pé, Ta ni yóò tan Áhábù láti kọlu Ramoti-Gílíádì Kí ó sì tọ ikú rẹ̀ lọ níbẹ̀ Ẹnìkan wí báyìí, ẹlòmíràn sì sọ mìíràn Ẹ̀mí kan sì jáde wá, ó sì dúró níwájú Olúwa , ó sì wí pé, Èmi yóò tàn án Olúwa sì béèrè pé, Báwo Ó sì wí pé,  Èmi yóò jáde lọ, èmi yóò sì di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì rẹ̀ Olúwa sì wí pé, Ìwọ yóò tàn án, ìwọ yóò sì borí, jáde lọ, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu gbogbo àwọn wòlíì rẹ wọ̀nyí Olúwa sì ti sọ ibi sí ọ Nígbà náà ni Ṣedekíàh ọmọ Kénáánà sì dìde, ó sì gbá Míkáyàh lójú, ó sì wí pé, Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Olúwa gbà lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀ Míkáyà sì wí pé, Ìwọ yóò rí i ní ọjọ́ náà, nígbà tí ìwọ yóò lọ láti inú ìyẹ̀wù dé ìyẹ̀wù láti fi ara rẹ pamọ́ Ọba Ísírẹ́lì sì pàṣẹ pé, Ẹ mú Míkáyà, kí ẹ sì mú un padà sọ́dọ̀ Ámónì, olórí ìlú, àti sọ́dọ̀ Jóásì ọmọ ọba kí ẹ sì wí pé, Báyìí ni ọba wí Ẹ fi eléyìí sínú túbú, kí ẹ sì fi oúnjẹ ìpọ́njú àti omi ìpọ́njú bọ́ ọ, títí èmi yóò fi padà bọ̀ ní àlàáfíà   Míkáyà sì wí pé, Bí ìwọ bá padà bọ̀ ní àlàáfíà, Olúwa kò ti ipa mi sọ̀rọ̀ Ó sì tún wí pé, Ẹ kíyèsí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo! Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì àti Jèhósáfátì ọba Júdà gòkè lọ sí Ramoti-Gílíádì Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún Jèhósáfátì pé, Èmi yóò pa aṣọ dà, èmi yóò sì lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wọ aṣọ ìgúnwà rẹ Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì pa aṣọ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà Ọba Árámù ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ méjìlélọ́gbọ̀n wí pé, Ẹ má ṣe bá ẹnìkankan jà, ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, bí kò ṣe ọba Ísírẹ́lì nìkan Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí Jèhósáfátì, wọ́n sì wí pé, Dájúdájú ọba Ísírẹ́lì ni èyí Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ì yípadà láti bá a jà, ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhósáfátì sì kígbe sókè, àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí i pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, wọ́n sì padà kúrò lẹ́yìn rẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹnìkan sì fa ọrun rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, ó sì ta ọba Ísírẹ́lì láàrin ìpàdé ẹ̀wù irin Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, Yí ọwọ́ rẹ dà, kí o sì mú mi jáde kúrò nínú ogun Èmi ti gbọgbẹ́ Ogun náà sì le ní ọjọ́ náà, a sì dá ọba dúró nínú kẹ̀kẹ́ kọjú sí àwọn ará Árámù Ẹ̀jẹ̀ sì sàn jáde láti inú ọgbẹ́ rẹ̀ sí àárin kẹ̀kẹ́ náà, ó sì kú ní àṣálẹ́ A sì kéde la ibùdó já ní àkókò ìwọ̀ oòrùn wí pé, Olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀ àti olúkúlùkù sí ilẹ̀ rẹ̀! Bẹ́ẹ̀ ni ọba kú, a sì gbé e wá sí Samáríà, wọ́n sì sin ín ní Samáríà Wọ́n sì wẹ kẹ̀kẹ́ náà ní adágún Samáríà, àwọn ajá sì lá ẹ̀jẹ̀ rè, àwọn àgbérè sì wẹ ara wọn nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti sọ Níti ìyókù ìṣe Áhábù, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, àti ilé eyin-erin tí ó kọ́, àti gbogbo ìlú tí ó tẹ̀dó, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì Áhábù sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ Áhásáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Jèhósáfátì ọmọ Áṣà, sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba lórí Júdà ní ọdún kẹrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì Jèhósáfátì sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ń jọba ní ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ní Jérúsálẹ́mù Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ásúbà ọmọbìnrin Sílíhì Ó sì rìn nínú gbogbo ọ̀nà Áṣà baba rẹ̀, kò sì yípadà kúrò nínú rẹ̀ ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Olúwa Kìkì àwọn ibi gíga ni a kò mú kúrò, àwọn ènìyàn sì ń rú ẹbọ, wọ́n sì ń sun tùràrí níbẹ̀ Jèhósáfátì sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ọba Ísírẹ́lì Níti ìyókù ìṣe Jèhósáfátì àti ìṣe agbára rẹ̀ tí ó ṣe, àti bí ó ti jagun sí, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà Ó pa ìyókù àwọn tí ń hùwà panṣágà ní ọjọ́ Áṣà bàbá rẹ̀ run kúrò ní ilẹ̀ náà Nígbà náà kò sí ọba ní Édómù adelé kan ni ọba Jèhósáfátì kan ọkọ̀ Táríṣíṣì láti lọ sí Ófírì fún wúrà, ṣùgbọ́n wọn kò lọ nítorí àwọn ọkọ̀ náà fọ́ ní Ésíónì-Gébérì Ní ìgbà náà Áhásáyà ọmọ Áhábù wí fún Jáhósáfátì pé, Jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ nínú ọkọ̀, ṣùgbọ́n Jèhósáfátì kọ̀ Nígbà náà ni Jèhósáfátì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dáfídì, baba rẹ Jéhórámù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Áhásáyà ọmọ Áhábù bẹ̀rẹ̀ sí jọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà ní ọdún kẹtàdínlógún Jèhósáfátì ọba Júdà, ó sì jọba ní ọdún méjì lórí Ísírẹ́lì Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa , nítorí tí ó rìn ní ọ̀nà baba rẹ̀, àti ní ọ̀nà ìyá rẹ̀, àti ní ọ̀nà Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó mú Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀ Ó sì sin Báálì, ó sì ń bọ Báálì, ó sì mú Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú, gẹ́gẹ́ bí i baba rẹ̀ ti ṣe Sólómónì Béèrè Fún Ọgbọ́n Sólómónì sì bá Fáráò ọba Éjíbítì dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó Ó sì mú-un wá sí ìlú Dáfídì títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹ́ḿpìlì Olúwa , àti odi tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń rú ẹbọ ní ibi gíga, nítorí a kò tíì kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa títí di ìgbà náà Sólómónì sì fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí Olúwa nípa rírìn gẹ́gẹ́ bí òfin Dáfídì baba rẹ̀, àti pé, ó rú ẹbọ, ó sì fi tùràrí jóná ní ibi gíga Ọba sì lọ sí Gíbíónì láti rúbọ, nítorí ibẹ̀ ni ibi gíga tí ó ṣe pàtàkì jù, Sólómónì sì rú ẹgbẹ̀rún ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Ní Gíbíónì Olúwa fi ara han Sólómónì lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì wí pé, Béèrè fún ohunkóhun tí o bá ń fẹ́ kí èmi ó fi fún ọ Sólómónì sì dáhùn wí pé, O ti fi inú rere oore ńlá hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dáfídì baba mi, nítorí ó jẹ́ olóòtọ́ sí ọ àti olódodo àti ẹni tí ó ní ọkàn ìdúró ṣinṣin Ìwọ sì tẹ̀ṣíwájú nínú oore ńlá yìí fún un, ìwọ sì ti fún un ní ọmọkùnrin láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ ní gbogbo ọjọ́ Nísinsìnyìí, Olúwa Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jọba ní ipò Dáfídì baba mi Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ̀ bí mo ṣe lè ṣe àwọn ojúṣe mi Ìránṣẹ́ rẹ nìyí láàrin àwọn ènìyàn tí o ti yàn, àwọn ènìyàn ńlá, wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò sì lè kà wọ́n tàbí mòye wọn Nítorí náà fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti le ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ àti láti mọ ìyàtọ̀ láàrin rere àti búburú Nítorí ta ni ó lè ṣe àkóso àwọn ènìyàn ńlá rẹ yìí Inú Olúwa sì dùn pé Sólómónì béèrè nǹkan yìí Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún-un pé, Nítorí tí ìwọ ti béèrè fún èyí, tí kì í ṣe ẹ̀mí gígùn tàbí ọrọ̀ fún ara rẹ, tàbí béèrè fún ikú àwọn ọ̀ta rẹ, ṣùgbọ́n fún òye láti mọ ẹjọ́ dá, èmi yóò ṣe ohun tí ìwọ ti béèrè Èmi yóò fún ọ ní ọgbọ́n àti ọkàn ìmòye, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ẹnìkan tí ó dà bí rẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò dìde tí yóò dà bí rẹ lẹ́yìn rẹ Ṣíwájú síi, èmi yóò fi ohun tí ìwọ kò bèrè fún ọ ọrọ̀ àti ọlá ní gbogbo ayé rẹ tí kì yóò sí ẹnìkan nínú àwọn ọba tí yóò dà bí rẹ Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dáfídì baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn Sólómónì jí ó sì mọ̀ pé àlá ni Ó sì padà sí Jérúsálẹ́mù, ó sì dúró níwájú àpótí májẹ̀mú Olúwa , ó sì rúbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ àlàáfíà Nígbà náà ni ó ṣe àṣè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ Lẹ́yìn náà ni àwọn obìnrin alágbérè méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ Ọ̀kan nínú wọn sì wí pé, Olúwa mi, èmi àti obìnrin yìí ń gbé nínú ilé kan Èmi sì bí ọmọ ní ilé pẹ̀lú rẹ̀ Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ìgbà tí mo bímọ tan, obìnrin yìí sì bímọ pẹ̀lú A sì nìkan dá wà kò sí ẹlòmíràn ní ilé bí kò ṣe àwa méjèèjì nìkan Ní òru, ọmọ obìnrin yìí kú nítorí tí ó sùn lé e Nígbà náà ni ó sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó sì gbé ọmọ tèmi lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nígbà tí èmi ìránṣẹ́ rẹ ti sùn lọ Ó sì tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sí àyà mi Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì mo sì dìde láti fi ọmú fún ọmọ mi ó sì ti kú! Ṣùgbọ́n nígbà tí mo sì wò ó fín ní òwúrọ̀, mo sì ríi pé kì í ṣe ọmọ mi tí mo bí Obìnrin kejì sì wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí alààyè ni ọmọ mi, èyí òkú ni ọmọ tirẹ̀ Èyí òkú ni tirẹ̀ èyí alààyè ni tèmi Ṣùgbọ́n èyí àkọ́kọ́ tún wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí òkú ni tìrẹ èyí alààyè ni tèmi Báyìí ni wọ́n sì ń jiyàn níwájú ọba Ọba sì wí pé, Ẹni yìí wí pé, Ọmọ mi ni ó wà láàyè, ọmọ tirẹ̀ ni ó kú, nígbà tí ẹni èkejì náà ń wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́! Ọmọ tirẹ̀ ni ó kú, ọmọ tèmi ni ó wà láàyè   Nígbà náà ni ọba wí pé, Ẹ mú idà fún mi wá Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú idà wá fún ọba Ọba sì pàṣẹ pé Ẹ gé alààyè ọmọ sí méjì, kí ẹ sì mú ìdajì fún ọ̀kan, àti ìdajì fún èkejì Obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ wà láàyè sì kún fún àánú fún ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, Jọ̀wọ́, Olúwa mi, ẹ fún un ní alààyè ọmọ! Ẹ má ṣe pa á! Ṣùgbọ́n obìnrin èkejì sì wí pé, Kì yóò jẹ́ tèmi tàbí tìrẹ̀ Ẹ gé e sí méjì! Nígbà náà ni ọba dáhùn, ó wí pé, Ẹ fi alààyè ọmọ fún obìnrin àkọ́kọ́ Ẹ má ṣe pa á òun ni ìyá rẹ̀ Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, wọ́n sì bẹ̀rù níwájú ọba, nítorí wọ́n ti rí í pé ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe ìdájọ́ Àwọn Aláṣẹ Àti Alákòóso Sólómónì Sólómónì ọba sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè rẹ̀ Ásáríyà ọmọ Ṣádókù àlùfáà Élíhóréfù àti Áhíjà àwọn ọmọ Ṣísánì akọ̀wé Jèhósáfátì ọmọ Áhílúdì ni akọ̀wé ìlú Bénáyà ọmọ Jéhóíádà ni olórí ogun Sádókù àti Ábíátarì ni àwọn àlùfáà Ásáríyà ọmọ Nátanì ni olórí àwọn agbègbè Sóbúdù ọmọ Nátanì, àlùfáà àti olùgba ọba ní ìmọ̀ràn Áhísárì ni olùtọ́jú ààfin Ádónírámù ọmọ Ábídà ni ó ń ṣe olórí iṣẹ́-ìlú Sólómónì sì tún ní ìjòyè méjìlá lórí gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀ Olúkúlùkù ní láti pèsè fún oṣù kan ní ọdún Orúkọ wọn ni wọ̀nyí Bénhúrì ní ìlú olókè Éfúráímù Beni-Dékérì ní Mákásì, Ṣáíbímù, Bẹti-Sémésì, àti Eloni-Bétíhánánì Beni-Hésédì, ní Árúbótì tirẹ̀ ni Sókò àti gbogbo ilẹ̀ Héférì ń ṣe Beni-Ábínádábù, ní Napoti Dórì òun ni ó fẹ́ Táfátì ọmọbìnrin Sólómónì ní aya Báánà ọmọ Áhílúdì, ní Táánákì àti Mégídò, àti ní gbogbo Bétísánì tí ń bẹ níhà Saritanà níṣàlẹ̀ Jésérẹ́lì, láti Bétísánì dé Abeli-Méhólà títí dé ibi tí ń bẹ ní ìkọjá Jókínéámù Bẹni-Gébérì ní Rámótì-Gílíádì tirẹ̀ ni àwọn ìletò Jáírì ọmọ Mànásè tí ń bẹ ní Gílíádì, tirẹ̀ sì ni agbégbé Ágóbù, tí ń bẹ ní Básánì, ọgọ́ta ìlú tí ó tóbi pẹ̀lú odi tí ẹnu ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ irin Áhínádábù ọmọ Ídò ní Máhánáímù Áhímásì ní Náfítalì ó fẹ́ Básémátì ọmọbìnrin Sólómónì ní aya Báánà ọmọ Húṣáì ní Ásérì àti ní Álótì Jèhósáfátì ọmọ Párúhà ni ó wà ní Ísákárì Síméì ọmọ Élà ni Bẹ́ńjámínì Gébérì ọmọ Úrì ní Gílíádì orílẹ̀ èdè Ṣíhónì ọba àwọn ará Ámórì àti orílẹ̀ èdè Ógù ọba Básánì Òun nìkan ni ìjòyè lórí ilẹ̀ náà Àwọn ènìyàn Júdà àti ti Ísírẹ́lì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí òkun wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń yọ ayọ̀ Sólómónì sì ń ṣàkóso lórí gbogbo àwọn ijọba láti odò Éjíbítì títí dé ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì, àti títí dé etí ilẹ̀ Éjíbítì Àwọn orílẹ̀ èdè yìí ń mú owó òde wá, wọ́n sì ń sin Sólómónì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ Oúnjẹ Sólómónì fún ọjọ́ kan jásí ọgbọ̀n ìyẹ̀fun kíkúná àti ọgọ́ta òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun, Màlúù mẹ́wàá tí ó sanra, àti ogún màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti egbin, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra Nítorí òun ni ó ṣakóso lórí gbogbo agbègbè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Éfúrátì, láti Tífísà títí dé Gásà, ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo ìlú tí ó káàkiri Nígbà ayé Sólómónì, Júdà àti Ísírẹ́lì, láti Dánì títí dé Béríṣébà, wọ́n ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ Sólómónì sì ní ẹgbàajì ilé ẹsin fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ẹgbàafà ẹlẹ́sin Àwọn ìjòyè agbègbè, olúkúlùkù ní oṣù rẹ̀, ń pèsè oúnjẹ fún Sólómónì ọba àti gbogbo àwọn tí ń wá síbi tábìlì ọba, wọ́n sì ríi pé ohun kankan kò ṣẹ́ kù Wọ́n tún máa ń mú ọkà báálì àti kóríko fún ẹsin àti fún ẹsin sísáré wá pẹ̀lú sí ibi tí ó yẹ, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìlànà tirẹ̀ Ọlọ́run sì fún Sólómónì ní ọgbọ́n, àti òye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti ìmọ̀ gbígbòrò òye tí a kò le è fi wé iyanrìn tí ó wà létí òkun Ọgbọ́n Sólómónì sì pọ̀ ju ọgbọ́n ọkùnrin ìlà-oòrùn lọ, ó sì pọ̀ ju gbogbo ọgbọ́n Éjíbítì lọ Ó sì ní òye ju gbogbo ènìyàn lọ, ju Étanì, ará Ésírà, àti Hémánì àti Kálíkólì, àti Darà àwọn ọmọ Máhólì lọ Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀ èdè yíká Ó sì pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti Kédárì tí ń bẹ ní Lébánónì dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja Àwọn ènìyàn sì ń wá láti gbogbo orílẹ̀ èdè láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómónì, tí àwọn ọba ayé ń rán, tí ó ti gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀ Ìmúrasílẹ̀ Láti Kọ́ Ilé Fún Nígbà tí Hírámù ọba Tírè sì gbọ́ pé a ti fi òróró yan Sólómónì ní ọba ní ipò Dáfídì bàbá rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Sólómónì, nítorí ó ti fẹ́ràn Dáfídì ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo Sólómónì sì ránṣẹ́ yìí padà sí Hírámù pé Ìwọ mọ̀ pé Dáfídì bàbá mi kò le kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, nítorí ogun tí ó wà yí i káàkiri, títí Olúwa fi fi gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀ ṣábẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀ rẹ̀ Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí Olúwa Ọlọ́run mi ti fún mi ní ìsinmi ní ibi gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ọ̀tá tàbí ìjàǹbá kan tí ó ṣe Nítorí náà mo gbèrò láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi, bí Olúwa ti sọ fún Dáfídì bábá mi, nígbà tí ó wí pé, Ọmọ rẹ tí èmi yóò gbé ka orí ìtẹ́ rẹ ní ipò rẹ ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi Nítorí náà ni kí o pàṣẹ pé kí wọn kí ó gé igi Kédárì Lébánónì fún mi wá Àwọn ènìyàn mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú tìrẹ, Èmi yóò sì san owó ọ̀yà tí ìwọ bá ránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn rẹ Ìwọ mọ̀ pé, a kò ní ẹnìkan nínú wa tí ó mọ bí a ti ń gé igi bí àwọn ará Ṣídónì Nígbà tí Hárámù sì gbọ́ iṣẹ́ Sólómónì, inú rẹ̀ sì dùn gidigidi, ó sì wí pé, Ògo ni fún Olúwa lónìí, nítorí tí ó ti fún Dáfídì ní ọlọgbọ́n ọmọ láti sàkóso àwọn ìlú ńlá yìí Hírámù sì ránṣẹ́ sí Sólómónì pé Èmi ti gbọ́ iṣẹ́ tí ìwọ rán sí mi, èmi yóò sì ṣe gbogbo èyí tí o fẹ́ ní pípèsè igi Kédárì àti ní ti igi fírì Àwọn ènìyàn mi yóò mú igi náà sọ̀kalẹ̀ láti Lébánónì wá sí òkun, èmi ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọ ní fífò lójú omi òkun títí dé ibi tí ìwọ ó na ìka sí fún mi Níbẹ̀ ni èmi yóò ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ìwọ yóò sì kó wọn lọ Ìwọ yóò sì gba ìfẹ́ mi nípa pípèsè oúnjẹ fún ilé mi Báyìí ni Hírámù sì pèsè igi Kédárì àti igi fírì tí Sólómónì ń fẹ́ fún un, Sólómónì sì fún Hírámù ní ẹgbàawá òṣùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún òṣùwọ̀n òróró dáradára Sólómónì sì ń tẹ̀ṣíwájú láti ṣe èyí fún Hírámù lọ́dọọdún Olúwa sì fún Sólómónì ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrin Hírámù àti Sólómónì, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn Sólómónì ọba sì sa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Ísírẹ́lì àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún ènìyàn Ó sì rán wọn lọ sí Lébánónì, ẹgbàárún lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lébánónì, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì Ádónírámù ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà Sólómónì sì ní ẹgbàá márùndínlógójì ènìyàn tí ń ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin gbẹ́nàgbẹ́nà lórí òkè, àti àwọn ìjòyè nínú àwọn tí a fi ṣe olórí iṣẹ́ Sólómónì jẹ́ ẹgbẹ̀rindínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún ènìyàn, tí ó ń ṣe aláṣẹ àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ náà Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú òkúta wá, òkúta iyebíye, àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ ilé náà lé ilẹ̀ Àwọn oníṣọ̀nà Sólómónì àti Hírámù àti àwọn ènìyàn Gébálì sì gbẹ́ wọn, wọ́n sì pèsè igi àti òkúta láti fi kọ́ ilé náà Sólómónì Kọ́ Ilé Náà Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún l ẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ní ọdún kẹrin ìjọba Sólómónì lórí Ísírẹ́lì, ní oṣù Sífì, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé Olúwa Ilé náà tí Sólómónì ọba kọ́ fún Olúwa sì jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gíga Ìloro níwájú tẹ́ḿpìlì ilé náà, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, ìbú ilé náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti iwájú ilé náà Ó sì ṣe fèrèsé tí kò fẹ̀ fún ilé náà Lára ògiri ilé náà ni ó bu yàrá yíká àti tẹ́ḿpìlì àti ibi mímọ́ jùlọ ni ó sì ṣe yàrá yíká Yàrá ìsàlẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní ìbú, ti àárin sì jẹ́ ìgbọ̀wọ́ mẹ́fà ní ìbú, àti ẹ̀kẹta ìgbọ̀nwọ́ méje sì ni ìbú rẹ̀ Nítorí lóde ilé náà ni ó dín ìgbọ̀nwọ́ kọ́ọ̀kan káàkiri, kí igi àjà kí ó má ba à wọ inú ògiri ilé náà Ní kíkọ́ ilé náà, òkúta tí a ti gbẹ́ sílẹ̀ kí a tó mú-un wá ibẹ̀ nìkan ni a lò, a kò sì gbúròó òòlù tàbí àáké tàbí ohun èlò irin kan nígbà tí a ń kọ́ ọ lọ́wọ́ Ẹnu-ọ̀nà yàrá ìṣàlẹ̀ sì wà ní ìhà gúṣù ilé náà wọ́n sì fi àtẹ̀gùn tí ó lórí gòkè sínú yàrá àárin, àti láti yàrá àárin bọ́ sínú ẹ̀kẹ́ta Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀, ó sì bo ilé náà pẹ̀lú àwọn ìtí igi àti pákó Kédárì Ó sì kọ́ yàrá ẹ̀gbẹ́ sí gbogbo ilé náà Gígùn ìkọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún, ó sì so wọ́n mọ́ ilé náà pẹ̀lú ìtì igi Kédárì Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sólómónì wá wí pé Níti ilé yìí tí ìwọ ń kọ́ lọ́wọ́, bí ìwọ bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ìwọ sì ṣe ìdájọ́ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́ láti máa ṣe wọ́n, Èmi yóò mú ìlérí tí mo ti ṣe fún Dáfídì baba rẹ̀ ṣẹ nípa rẹ̀ Èmi yóò sì máa gbé àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èmi kì ó sì kọ Ísírẹ́lì ènìyàn mi Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀ Ó sì fi pákó Kédárì tẹ́ ògiri ilé náà nínú, láti ilẹ̀ ilé náà dé àjà rẹ̀, ó fi igi bò wọ́n nínú, ó sì fi pákó fírì tẹ́ ilẹ̀ ilé náà Ó pín ogún ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ilẹ̀ dé àjà ilé ni ó fi pákó kọ́, èyí ni ó kọ sínú, fún ibi tí a yà sí mímọ́ àní ibi mímọ́ jùlọ Ní iwájú ilé náà, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀ jẹ́ Inú ilé náà sì jẹ́ Kédárì, wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà rẹ̀ pẹ̀lú ìtàkùn àti ìtànná Gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ Kédárì a kò sì rí òkúta kan níbẹ̀ Ó sì múra ibi mímọ́ jùlọ sílẹ̀ nínú ilé náà láti gbé àpótí májẹ̀mú Olúwa ka ibẹ̀ Nínú ibi mímọ́ náà sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga Ó sì fi kìkì wúrà bo inú rẹ̀ ó sì fi igi Kédárì bo pẹpẹ rẹ̀ Sólómónì sì fi kìkì wúrà bo inú ilé náà, ó sì tan ẹ̀wọ̀n wúrà dé ojú ibi mímọ́ jùlọ, ó sì fi wúrà bò ó Gbogbo ilé náà ni ó fi wúrà bò títí ó fi parí gbogbo ilé náà, àti gbogbo pẹpẹ tí ó wà níhà ibi mímọ́ jùlọ, ni ó fi wúrà bò Ní inú-ibi-mímọ́ jùlọ ni ó fi igi ólífì ṣe kérúbù méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga Apá kérúbù kìn-ní-ní sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gíga, àti apá kérúbù kejì ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti ṣóńṣó apá kan dé ṣóńṣó apá kejì Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá sì ni kérúbù kejì pẹ̀lú, nítorí kérúbù méjèèje jọ ara wọn ní ìwọ̀n ní títóbi àti títẹ̀wọ̀n bákan náà Gíga kérúbù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá Ó sì gbé àwọn kérúbù náà sínú ilé ti inú lọ́hùn ún, pẹ̀lú ìyẹ́ apá wọn ní nínà jáde Ìyẹ́ apá kérúbù kan sì kan ògiri kan, nígbà tí ìyẹ́-apá èkejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá wọn sì kan ara wọn láàrin yàrá náà Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà Lára àwọn ògiri tí ó yí ilé náà ká, nínú àti lóde, ó sì ya àwòrán àwọn kérúbù síi àti ti igi ọ̀pẹ, àti ti ìtànná ewéko Ó sì tún fi wúrà tẹ́ ilẹ̀ ilé náà nínú àti lóde Nítorí ojú ọ̀nà ibi-mímọ́-jùlọ ni ó ṣe ilẹ̀kùn igi ólífì sí pẹ̀lú àtẹ́rígbà àti òpó ìhà jẹ́ ìdámárùn-ún ògiri Àti lára ilẹ̀kùn igi ólífì náà ni ó ya àwòrán àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí, ó sì fi wúrà bò wọ́n, ó sì tan wúrà sí ara àwọn kérúbù àti sí ara igi ọ̀pẹ Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe òpó igi ólífì onígun mẹ́rin fún ilẹ̀kùn ilé náà Ó sì tún fi igi fírì ṣe ilẹ̀kùn méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ewé méjì tí ó yí sí ihò ìtẹ̀bọ̀ Ó sì ya àwòrán kérúbù, àti ti igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí ara wọn, ó sì fi wúrà bò ó, èyí tí ó tẹ́ sórí ibi tí ó gbẹ́ Ó sì fi ẹṣẹṣẹ òkúta mẹ́ta gbígbẹ, àti ẹṣẹ kan ìtí kédárì kọ́ àgbàlá ti inú lọ́hùn ún Ní ọdún kẹrin ni a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lé ilẹ̀, ní oṣù Sífì Ní ọdún kọkànlá ní oṣù Búlù, oṣù kẹjọ, a sì parí ilé náà jálẹ̀ jálẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpín rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó yẹ Ó sì lo ọdún méje ní kíkọ́ ilé náà Sólómónì Kọ́ Ààfin Rẹ̀ Sólómónì sì lo ọdún mẹ́talá láti fi kọ́ ààfin rẹ̀, ó sì parí gbogbo iṣẹ́ ààfin rẹ̀ Ó kọ́ ilé igbó Lébánónì pẹ̀lú gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn ún ìgbọ̀nwọ́, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọwọ́ mẹ́rin igi kédárì, àti ìdábú igi kédárì lórí òpó náà A sì fi igi kédárì tẹ́ ẹ lókè lórí yàrá tí ó jókòó lórí ọ̀wọ̀n márùnlélógójì, mẹ́ẹ̀dógún ní ọ̀wọ́ Fèrèsé rẹ̀ ni a gbé sókè ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, kọjú sí ara wọn Gbogbo ilẹ̀kùn àti òpó sì dọ́gba ní igun mẹ́rin wọ́n sì wà ní apá iwájú ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, wọ́n kọjú sí ara wọn Ó sì fi ọ̀wọ̀n ṣe gbàngàn ìdájọ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ Ìloro kan sì wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀n àti ìbòrí ìgúnwà níwájú wọn Ó sì ṣe gbàngàn ìtẹ́, gbàngàn ìdájọ́, níbi tí yóò ti ṣe ìdájọ́, ó sì fi igi kédárì bò ó láti ilẹ̀ dé àjà ilé Ààfin rẹ̀ níbi tí yóò sì gbé wà ní àgbàlá lẹ́yìn ààfin, irú kan náà ni wọ́n Sólómónì sì kọ́ ààfin tí ó rí bí gbàngàn yìí fún ọmọbìnrin Fáráò tí ó ní ní aya Gbogbo wọ̀nyí láti òde dé apá àgbàlá ńlá, àti láti ìpìlẹ̀ dé ìbòrí òkè ilé, wọ́n sì jẹ́ òkúta iyebíye gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n òkúta gbígbẹ, tí a fi ayùn rẹ́ nínú àti lóde Ìpìlẹ̀ náà jẹ́ òkúta iyebíye, àní òkúta ńlá ńlá, àwọn mìíràn wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ̀wàá, àwọn mìíràn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ Lókè ni òkúta iyebíye wà nípa ìwọ̀n òkúta tí a gbé àti igi kédárì Àgbàlá ńlá náà yíkákiri ògiri pẹ̀lú ọ̀wọ́ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ọ̀wọ́n kan igi ìdábùú ti kédárì, bí ti inú lọ́hùn ún àgbàlá ilé Olúwa pẹ̀lú ìloro rẹ̀ Sólómónì ọba ránṣẹ́ sí Tírè, ó sì mú Hírámù wá, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ opó láti inú ẹ̀yà Náfítalì àti tí baba rẹ̀ sì ṣe ará Tírè, alágbẹ̀dẹ idẹ Hírámù sì kún fún ọgbọ́n àti òye, àti ìmọ̀ láti ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ idẹ Ó wá sọ́dọ̀ Sólómónì ọba, ó sì ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un Ó sì dá ọ̀wọ̀n idẹ méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún ní gíga okùn ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ni ó sì yí wọn ká Ó sì tún ṣe ìparí méjì ti idẹ dídá láti fi sókè àwọn ọ̀wọ̀n náà, ìparí kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gíga Onírúurú iṣẹ́, àti ohun híhun ẹ̀wọ̀n fún àwọn ìparí tí ń bẹ lórí àwọn ọ̀wọ̀n náà, méje fún ìparí kọ̀ọ̀kan Ó sì ṣe àwọn Pómégíránátè ní ọ̀wọ́ méjì yíkákiri lára iṣẹ́ ọ̀wọ̀n náà, láti fi bo àwọn ìparí ti ń bẹ lókè, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìparí kejì Àwọn ìparí tí ń bẹ ní òkè àwọn ọ̀wọ̀n náà tí ń bẹ ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ náà dàbí àwòrán lílì, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga Lórí àwọ̀n ìparí ọ̀wọ́n méjì náà lókè, wọ́n sì súnmọ́ ibi tí ó yẹ lára ọ̀wọ̀n tí ó wà níbi iṣẹ́ àwọ̀n, wọ́n sì jẹ́ igba pómégíránátè ní ọ̀wọ́ yíkákiri Ó sì gbé àwọn ọ̀wọn náà ró ní ìloro tẹ́ḿpìlì, ó sì pe orúkọ ọ̀wọ̀n tí ó wà ní gúṣù ní Járánì àti èyí tí ó wà ní àríwá ní Bóásì Àwọn ìparí lókè sì jẹ́ àwòrán lílì Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ti àwọn ọ̀wọ̀n sì parí Ó sì ṣe agbádá dídá, ó ṣe bíríkítí, ó wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé èkejì àti ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gíga rẹ̀ Ó sì gba okùn ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ láti wọ̀n yíí ká Ní ìṣàlẹ̀ etí rẹ̀, kókó wà yíi ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan Ó yí agbádá náà káàkiri, a dá kókó náà ní ọ̀wọ́ méjì, nígbà tí a dá a Ó sì dúró lórí màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta sì kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúṣù, mẹ́ta sì kọjú sí ìlà oòrùn Agbada náà sì jókòó lórí wọn, gbogbo apá ẹ̀yìn wọn sì ń bẹ nínú Ó sì nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ago, bí ìtànná lílì Ó sì gba ẹgbàá ìwọ̀n Bátì Ó sì tún ṣe ẹṣẹ̀ idẹ tí a lè gbé mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga Báyìí ni a sì ṣe ẹsẹ̀ náà Wọ́n ní àlàfo ọnà àárin tí a so mọ́ agbede-méjì ìpàdé etí Lórí àlàfo ọnà àárin tí ó wà lágbedeméjì ni àwòrán kìnnìún, màlúù, àti àwọn kérúbù wà, àti lórí ìpàdé etí bákan náà Lókè àti nísàlẹ̀ àwọn kìnnìún, màlúù sì ni iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà Ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ni kẹ̀kẹ́ idẹ mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀pá kẹ̀kẹ́ idẹ, ọ̀kọ̀ọ̀kan ni ó ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ lábẹ́, tí a gbẹ́, iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà ní ìhà gbogbo rẹ̀ Nínú ẹsẹ̀ náà ẹnu kan wà tí ó kọ bíríkítí tí ó jìn ní ìgbọ̀nwọ́ kan Ẹnu yìí ṣe róbótó àti pẹ̀lú iṣẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ Ní àyíká ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbígbẹ́ wà Àlàfo ọ̀nà àárin ẹsẹ̀ náà sì ní igun mẹ́rin, wọn kò yíká Kẹ̀kẹ́ mẹ́rin sì wà nísàlẹ̀ àlàfo ọ̀nà àárin a sì so ọ̀pá àyíká kẹ̀kẹ́ náà mọ́ ẹsẹ̀ náà Gíga àyíká kẹ̀kẹ́ kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ A sì ṣe àyíká kẹ̀kẹ́ náà bí i iṣẹ́ kẹ̀kẹ́ igi ìdalu, ibi ihò, ibi ìpàdé, àti ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn, gbogbo wọn sì jẹ́ irin dídà Ẹṣẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ mẹ́rin, ọ̀kan ní igun kọ̀ọ̀kan, tí ó yọrí jáde láti ẹṣẹ̀ Lókè ẹṣẹ̀ náà ni àyíká kan wà tí ó jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́ ní jíjìn Ẹ̀gbẹ́ etí rẹ̀ àti àlàfo ọ̀nà àárin rẹ̀ ni a ṣo mọ́ òkè ẹsẹ̀ náà Ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù, kìnnìún àti igi ọ̀pẹ sára ìhà orí rẹ̀ àti sára àlàfo ọ̀nà àárin, ní gbogbo ibi tí àyè wà, pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ yíkákiri Báyìí ni ó ṣe ṣe àwọn ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wàá Wọ́n sì gbẹ́ gbogbo wọn bákan náà, ìwọ̀n kan náà àti títóbi kan náà Nígbà náà ni ó ṣe agbádá idẹ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gbà tó ogójì ìwọ̀n Bátì, ó sì wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ni agbádá kọ̀ọ̀kan wà Ó sì fi ẹsẹ̀ márùn ún sí apá ọ̀tún ìhà gúṣù ilé náà àti márùn ún sí apá òsì ìhà àríwá Ó sì gbé agbádá ńlá ka apá ọ̀tún, ní apá ìlà oòrùn sí ìdojúkọ gúṣù ilé náà Ó sì tún ṣe ìkòkò, àti ọkọ́ àti àwo kòtò Bẹ́ẹ̀ ni Hírámù sì parí gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe fún ilé Olúwa fún Sólómónì ọba Àwọn ọ̀wọ̀n méjì Ọpọ́n méjì ìparí tí ó wà lókè àwọn ọ̀wọ̀n iṣẹ́ àwọn méjì ní láti bo ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ̀n Irínwó pómégíránátè fún iṣẹ́ àwọn méjì, ọ̀wọ́ méjì pómégíránátè fún iṣẹ́ àwọn kan láti bo àwọn ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ̀n Ẹṣẹ̀ mẹ́wàá pẹ̀lú agbádá mẹ́wàá wọn Agbada ńlá náà, àti màlúù méjìlá tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ Ìkòkò, ọkọ́ àti àwo kòtò Gbogbo ohun èlò wọ̀nyí tí Hírámù ṣe fún Sólómónì ọba nítorí iṣẹ́ Olúwa sì jẹ́ idẹ dídán Ọba sì dá wọn ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì lágbedeméjì Ṣúkótì àti Ṣárítanì Sólómónì sì jọ̀wọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí láìwọ̀n, nítorí tí wọ́n pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ ìwọ̀n idẹ Sólómónì sì tún ṣe gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ tí ń ṣe ti ilé Olúwa pẹ̀lú pẹpẹ wúrà tabílì wúrà lórí èyí tí àkàrà ìfihàn gbé wà Ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà, márùn-ún ní apá ọ̀tún àti márùn ún ní apá òsì, níwájú ibi mímọ́ jùlọ ìtànná ewéko fìtílà àti ẹ̀mú wúrà Ọpọ́n kìkì wúrà, àlùmágàjí fìtílà, àti àwo kòtò, àti ṣíbí àti àwo tùràrí ti wúrà dáradára àti àgbékọ́ wúrà fún ilẹ̀kùn inú ilé ibi mímọ́ jùlọ àti fún ilẹ̀kùn ilé náà, àní ti tẹ́ḿpìlì Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Sólómónì ọba ṣe fún ilé Olúwa parí, ó mú gbogbo nǹkan tí Dáfídì baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá fàdákà, wúrà àti ohun èlò, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé Olúwa A Gbé Àpótí-Ẹ̀rí Wá Sí Ilé Náà Nígbà náà ni Sólómónì pe àwọn àgbà Ísírẹ́lì àti gbogbo àwọn olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ papọ̀ níwájú rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù, láti gbé àpótí-ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa wá láti ìlú Dáfídì, tí ń ṣe Ṣíónì Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì pe ara wọn jọ sọ́dọ̀ Sólómónì ọba ní àkókò àjọ ọdún ní oṣù Étanímù tí íṣe osù kéje Nígbà tí gbogbo àwọn àgbà Ísírẹ́lì dé, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí-ẹ̀rí, wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa àti àgọ́ àjọ ènìyàn àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́ Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì sì gbé wọn gòkè wá, Àti Sólómónì ọba, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àpótí-ẹ̀rí, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àgùntàn àti màlúù tí a kò le mọ iye, àti tí a kò le kà rúbọ Àwọn àlùfáà sì gbé àpótí-ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀ sínú ibi tí a yà sí mímọ́, ibi mímọ́ ilé náà, jùlọ lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù Àwọn kérúbù na ìyẹ́ wọn méjèèjì sí ibi àpótí-ẹ̀rí, wọ́n sì bo àpótí-ẹ̀rí náà, àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ tí a fi ń gbé e Àwọn ọ̀pá yìí ga tó bẹ́ẹ̀ tí a fi le rí orí wọn láti ibi mímọ́ níwájú ibi tí a yà sí mímọ́, ṣùgbọ́n a kò sì rí wọn lóde ibi mímọ́, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí Kò sí ohun kankan nínú àpótí-ẹ̀rí bí kò ṣe tábìlì òkúta méjì tí Mósè ti fi sí ibẹ̀ ní Hórébù, níbi tí Olúwa ti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì Nígbà tí àwọn àlùfáà jáde láti ibi mímọ́, àwọ̀sánmà sì kún ilé Olúwa Àwọn àlùfáà kò sì le ṣiṣẹ́ wọn nítorí àwọ̀sánmà náà, nítorí ògo Olúwa kún ilé náà Nígbà náà ni Sólómónì sì wí pé, Olúwa ti wí pé, òun yóò máa gbé inú òkùnkùn biribiri Nítòótọ́ èmi ti kọ́ ilé kan fún ọ, ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láéláé Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì dúró síbẹ̀, ọba sì yí ojú rẹ̀, ó sì bùkún fún wọn Nígbà náà ni ó wí pé Ìbùkún ni fún Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ìlérí tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dáfídì bàbá mi ṣẹ Nítorí tí ó wí pé, Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Éjíbítì, èmi kò tí ì yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi láti wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n èmi ti yan Dáfídì láti ṣàkóso àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi Dáfídì baba mi sì ní i lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n Olúwa sì wí fún Dáfídì bàbá mi pé, Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi, ó dára láti ní èyí ní ọkàn rẹ Ṣùgbọ́n, ìwọ kọ ni yóò kọ́ ilé náà, ṣùgbọ́n ọmọ rẹ, tí ó tinú ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ jáde òun ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi Olúwa sì ti pa ìlérí rẹ̀ tí ó ṣe mọ́ Èmi sì ti rọ́pò Dáfídì bàbá mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì báyìí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí, èmi sì kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì Èmi sì ti pèsè ibìkan níbẹ̀ fún àpótí-ẹ̀rí, èyí tí í ṣe májẹ̀mú Olúwa tí ó ti bá àwọn baba wa dá nígbà tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá Sólómónì sì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa , níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè ọ̀run Ó sì wí pé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ lókè ọ̀run tàbí ní ìṣàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ tí ó pa májẹ̀mú àti àánú mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ O sì ti pa ìlérí rẹ mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì baba mi pẹ̀lú ẹnu rẹ ni ìwọ ṣe ìlérí, o sì mú u ṣẹ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, bí ó ti rí lónìí Ǹjẹ́ báyìí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, bá ìránṣẹ́ rẹ̀ Dáfídì bàbá mi pa ohun tí ìwọ ti ṣe ìlérí fún un mọ́ wí pé, Iwọ kì yóò kùnà láti ní ènìyàn kan láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ bá lè kíyèsí ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa rìn níwájú mi bí ìwọ ti rìn Ǹjẹ́ báyìí, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣe ìlérí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Dáfídì baba mi wá sí ìmúṣẹ Ṣùgbọ́n nítòótọ́ Ọlọ́run yóò máa gbé ayé bí Ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò le gbà ọ́ Kí a má sọ pé ilé yìí tí mo kọ́ fún ọ! Síbẹ̀ ṣe ìfetísílẹ̀ àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ fún àánú, Olúwa Ọlọ́run mi Gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ lónìí Jẹ́ kí ojú rẹ ṣí ṣí ilé yìí ní òru àti ní ọ̀sán, ibí yìí tí ìwọ ti wí pé, óorúkọ mi yóò wà níbẹ̀, nítorí ìwọ yóò gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ gbà sí ibí yìí Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí ibí yìí Gbọ́ láti ọ̀run wá láti ibùgbé rẹ, àti nígbà tí o bá gbọ́, dáríjìn Nígbà tí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì fi wá lée láti mú-un búra, bí ìbúra náà bá sì dé iwájú pẹpẹ rẹ ní ilé yìí, nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì ṣe Kí o sì ṣèdájọ́ láàrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ, dá ènìyàn búburú lẹ́bi, kí o sì mú wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe, dá olóòtọ́ láre, kí a sì fi ẹṣẹ̀ àìlẹ́bi rẹ̀ múlẹ̀ Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹ́gun Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ, nítorí tí wọ́n ti ṣẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá yípadà sí ọ, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ nínú ilé yìí nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ jìn-ní, kí o sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fún àwọn baba wọn Nígbà tí ọ̀run bá ṣé mọ́, tí kò sí òjò nítorí tí àwọn ènìyàn rẹ ti ṣẹ̀ sí ọ, bí wọ́n bá gbàdúrà sí ìhà ibí yìí, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí tí ìwọ ti pọ́n wọn lójú, nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jìn wọ́n, à ní Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ Kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ láti máa rìn, kí o sì rọ òjò sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fi fún ènìyàn rẹ fún ìní Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-àrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdú, eṣú tàbí kòkòrò tí ń jẹni run, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá bá dó tì wọ́n nínú àwọn ìlú wọn, irú ìpọ́njú tàbí àrùnkárùn tó lè wá, nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ ẹnìkan láti ọ̀dọ̀ gbogbo Ísírẹ́lì wá, tí olúkúlùkù sì mọ ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀, bí ó bá sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé yìí, nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ Dáríjìn, kí o sì ṣe sí olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ti ṣe, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ mọ ọkàn rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, Nítorí wọn yóò bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọn yóò wà ní ilẹ̀ tí ìwọ fi fún àwọn baba wa Níti àwọn àlejò tí kì í ṣe Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ rẹ, nítorí tí àwọn ènìyàn yóò gbọ́ orúkọ ńlá rẹ, àti ọwọ́ agbára rẹ, àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá sì wá, tí ó sì gbàdúrà sí ìhà ilé yìí, nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí àlejò náà yóò bèèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo ènìyàn ní ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì máa bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì le mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a fi pe ilé yìí tí mo kọ́ Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá jáde lọ sí ogun sí àwọn ọ̀ta wọn, níbikíbi tí ìwọ bá rán wọn, nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí Olúwa sí ìhà ìlú tí ìwọ ti yàn àti síhà ilé tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ, nígbà náà ni kí o gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró Nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ sí ọ, nítorí kò sí ẹnìkan tí kì í ṣẹ̀, tí ìwọ sì bínú sí wọn, tí ìwọ sì fi wọ́n lé ọ̀tá lọ́wọ́, tí ó kó wọn ní ìgbékùn lọ sí ilẹ̀ wọn, jínjìnnà tàbí nítòòsí bí wọ́n bá ní ìyípadà ọkàn ní ilẹ̀ níbi tí a kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n bá sì ronúpìwàdà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ sí ọ ní ilẹ̀ àwọn tí ó kó wọn ní ìgbékùn lọ, wí pé, Àwa ti ṣẹ̀, àwa ti ṣe ohun tí kò tọ́, àwa ti ṣe búburú bí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà àti gbogbo ọkàn wọn yípadà sí ọ, ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ sí ìhà ilẹ̀ wọn tí ìwọ ti fi fún àwọn baba wọn, Ìlú tí ìwọ ti yàn, àti ilé tí èmi kọ́ fún orúkọ rẹ Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn ní ọ̀run, ní ibùgbé rẹ, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró Kí o sì dáríjìn àwọn ènìyàn rẹ, tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ dárí gbogbo ìrékọjá wọn tí wọ́n ṣe sí ọ jì, kí o sì bá àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ wí, kí wọn kí ó lè ṣàánú fún wọn nítorí ènìyàn rẹ àti ìní rẹ ni wọ́n, àwọn ẹni tí ìwọ ti mú ti Éjíbítì jáde wá, láti inú irin ìléru Jẹ́ kí ojú rẹ sí sí ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, àti sí ẹ̀bẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, kí o sì tẹ́tí sílẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá kégbe sí ọ Nítorí tí ìwọ ti yà wọ́n kúrò nínú gbogbo orílẹ̀ èdè ayé, láti máa jẹ́ ìní rẹ, bí ìwọ ti sọ lati ọwọ́ Móṣè ìránṣẹ́ rẹ, nígbà tí ìwọ Olúwa Ọlọ́run mú àwọn baba wa ti Éjíbítì jáde wá Nígbà tí Sólómónì ti parí gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ yìí sí Olúwa tán, ó dìde kúrò lórí eékún rẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa níbi tí ó ti kúnlẹ̀ tí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run Ó sì dìde dúró ó sì fi ohùn rara súre fún gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì wí pé Ìbùkún ni fún Olúwa tí ó ti fi ìsinmi fún Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ̀ bí ó ti ṣèlérí Kò sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí rere tí ó ti ṣe láti ọwọ́ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ wá Kí Olúwa Ọlọ́run wa kí ó wà pẹ̀lú wa bí ó ti wà pẹ̀lú àwọn baba wa kí ó má sì ṣe fi wá sílẹ̀ tàbí kọ̀ wá sílẹ̀ Kí ó fa ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti máa rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, tí ó ti pàṣẹ fún àwọn bàbá wa Àti kí ó sì jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí, tí mo ti gbà ní àdúrà níwájú Olúwa , kí ó wà nítòsí Olúwa Ọlọ́run wa ní ọ̀sán àti ní òru, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró àti ọ̀rọ̀ Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àìní wa ojoojúmọ́, kí gbogbo ènìyàn ayé lè mọ̀ pé Olúwa òun ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ọkàn yín pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run wa, láti máa rìn nínú àṣẹ rẹ̀ àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, bí i ti òní yìí Nígbà náà ni ọba àti gbogbo Ísírẹ́lì rú ẹbọ níwájú Olúwa Sólómónì rú ẹbọ ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa ẹgbàá mọ́kànlá màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà àgùntàn Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn omọ Ísírẹ́lì ya ilé Olúwa sí mímọ́ Ní ọjọ́ kan náà ni ọba ya àgbàlá àárin tí ń bẹ níwájú ilé Olúwa sí mímọ́, níbẹ̀ ni ó sì rú ẹbọ ọrẹ sísun àti ọrẹ oúnjẹ, àti ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ń bẹ níwájú Olúwa kéré jù láti gba ọrẹ ṣíṣun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọrẹ ẹbọ àlàáfíà Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì ṣe àpèjọ nígbà náà, àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, àjọ ńlá ńlá ni, láti ìwọ Hámátì títí dé odò Éjíbítì Wọ́n sì sàjọyọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ijọ́ méje àti ijọ́ méje sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá papọ̀ Ní ọjọ́ kẹjọ ó rán àwọn ènìyàn lọ Wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn fún gbogbo ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀, àti fún Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀ Nígbà tí Solómónì sì parí kíkọ́ ilé Olúwa àti ààfin ọba, tí ó sì ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó ń fẹ́ láti ṣe, Olúwa sì farahàn án ní ìgbà kejì, bí ó ti farahàn án ní Gíbíónì Olúwa sì wí fún un pé Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ tí ìwọ ti bẹ̀ níwájú mi, mo ti ya ilé yìí sí mímọ́, tí ìwọ ti kọ́, nípa fífi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé Ojú mi àti ọkàn mi yóò wà níbẹ̀ nígbà gbogbo Bí ìwọ bá rìn níwájú mi ní ọkàn òtítọ́ àti ìdúró ṣinṣin, bí i Dáfídì baba rẹ ti rìn, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí mo ti paláṣẹ fún ọ àti kí o sì pa àṣẹ mi àti òfin mi mọ́, Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì títí láé, bí mo ti ṣe ìlérí fún Dáfídì baba rẹ nígbà tí mo wí pé, Ìwọ kì yóò kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n tí ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ẹ kò sì pa òfin mi mọ́ àti àṣẹ mi tí mo ti fi fún ọ, tí ẹ sì lọ láti sin Ọlọ́run mìíràn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n, nígbà náà ni èmi yóò ké Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ tí èmi fi fún wọn, èmi yóò sì kọ ilé yìí tí èmi ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi Nígbà náà ni Ísírẹ́lì yóò sì di òwe àti ìmúṣẹ̀sín láàrin gbogbo orílẹ̀ èdè Àti ilé yìí tí ó ga, ẹnu yóò sì ya olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá lẹ́bàá rẹ̀, yóò sì pòṣé, wọn ó sì wí pé, Èéṣe tí Olúwa fi ṣe irú nǹkan yìí sí ilẹ̀ yìí àti ilé yìí Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, tí ó mú àwọn bàbá wọn jáde láti Éjíbítì wá, wọ́n sì ti gbá Ọlọ́run mìíràn mú, wọ́n ń bọ wọ́n, wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyìí tí Olúwa ṣe mú gbogbo ìjàǹbá yìí wá sórí wọn   Lẹ́yìn ogún ọdún, nígbà tí Sólómónì kọ́ ilé méjèèjì yìí tan ilé Olúwa àti ààfin ọba Sólómónì ọba sì fi ogún ìlú ní Gálílì fún Hírámù ọba Tírè, nítorí tí Hírámù ti bá a wá igi kédárì àti igi fírì àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n nígbà tí Hírámù sì jáde láti Tírè lọ wo ìlú tí Sólómónì fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn Ó sì wí pé, Irú ìlú wo nì wọ̀nyí tí ìwọ fi fún mi, arákùnrin mi Ó sì pè wọ́n ní ilẹ̀ kábúlù títí fi di òní yìí Hírámù sì ti fi ọgọ́fà talẹ́ntì wúrà ránṣẹ́ sí ọba Ìdí àwọn asìnrú ti Sólómónì ọba kójọ ni èyí láti kọ́ ilé Olúwa àti ààfin òun tìkárarẹ̀ Mílò, odi Jérúsálẹ́mù, Hásórì, Mégídò àti Gésérì Fáráò ọba Éjíbítì sì ti kọlu Gésérì, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kénánì tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Sólómónì lọ́rẹ Sólómónì sì tún Gésérì kọ́, àti Bẹti Hórónì ìṣàlẹ̀, Àti Bálátì àti Támárì ní ihà, láàrin rẹ̀, Àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Sólómónì ní, àti ìlú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ìlú fún àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀, àti èyí tí ó ń fẹ́ láti kọ́ ní Jérúsálẹ́mù, ní Lébánónì àti ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ tí ó ń ṣe àkóso Gbogbo ènìyàn tí ó kù nínú àwọn ará Ámórì ará Hítì, Pérísì, Hífì àti Jébúsì, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ará Ísírẹ́lì, ìyẹn ni pé àwọn ọmọ wọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò le parun pátapáta, àwọn ni Sólómónì bu iṣẹ́ ìrú fún títí di òní yìí Ṣùgbọ́n, Sólómónì kò fi ẹnìkankan ṣe ẹrú nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àwọn ni ológun rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti àwọn balógun rẹ̀, àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ Àwọn sì tún ni àwọn olórí olùtọ́jú tí wọ́n wà lórí iṣẹ́ Sólómónì, àádọ́tàdínlẹ́gbẹ̀ta , ní ń ṣe àkóso lórí àwọn ènìyàn tí ń ṣe iṣẹ́ náà Lẹ́yìn ìgbà tí ọmọbìnrin Fáráò ti gòkè láti ìlú Dáfídì wá sí ààfin tí Sólómónì kọ́ fún un, nígbà náà ni ó kọ́ Mílò Nígbà mẹ́ta lọ́dún ni Sólómónì ń rú ẹbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ àlàáfíà lórí pẹpẹ tí ó tẹ́ fún Olúwa , ó sì sun tùràrí níwájú Olúwa pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó parí ilé náà Sólómónì ọba sì tún ṣe òwò ọkọ̀ ní Esioni-Gébérì, tí ó wà ní ẹ̀bá Élátì ní Édómù, létí òkun pupa Hírámù sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì Wọ́n sì dé ófírì, wọ́n sì mú irínwó ó lé ogún talẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Sólómónì ọba Ìyìn sí Ọlọ́run fún ìrètí tó wà láàyè Pétérù, Àpósítélì Jésù Kírísítì, Sí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ti wọ́n ń ṣe àtìpó ní àgbáyé, ti wọn tú káàkiri sí Pọ́ńtù, Gálátíà, Kápádókíà, Ésíà, àti Bítíníà, àwọn ẹni tí a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba, nípa ìsọdimímọ́ Ẹ̀mí, sí ìgbọ́ràn àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀ Jésù Kírísítì Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sì fún yín Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jésù Kírísítì Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlárẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jésù Kírísítì kúrò nínú òkú, àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í sá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin, Ẹ̀yin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyin Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀nbí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́ Àwọn wọ̀nyìí sì wáyé ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jésù Kírísítì Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jé pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo Ẹ̀yin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlá ọkàn yín Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wádìí jinlẹ̀ jinlẹ̀ pẹ̀lú ìbìkítà tí ó ga jùlọ Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sáà wo ni Ẹ̀mí Kírísítì tí ó wà nínú wọn ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kírísítì àti ògo tí yóò tẹ̀lé e Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkárawọn bí kò se fún ẹ̀yin, nígba tí wọ́n sọ nípa àwọn ohun tí ẹ ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ń wàásù ìyìnrere náà fún yín nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí ooe-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jésù Kírísítì Bí àwọn ọmọ tí ń ń gbọ́ràn, láìdá ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́ Nítorí a ti kọ ọ pé, Ẹ jẹ́ mímọ́ nítorí tí Èmi jẹ mímọ́! Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti ń képe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsáájú, ẹ máa lo ìgbà àtipó yin ni ìbẹ̀rù Níwọ̀nbí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín pàdà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n ani ẹ̀jẹ̀ Kírísítì Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹ́yìn wọ̀nyí nítorí yín, Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un kí ìgbàgbọ́ àti ìrétí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnikejì yín gidigidi láti ọkàn wá Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láàyè tí ó sì dúró Nítorí pé, Gbogbo ènìyàn dàbí kóríko, àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù, Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìyìn rere tí a wàásù fún yín Àpáta Ìyè Àti Ènìyàn Tí A Yàn Nítorí náà, ẹ fi àrankan gbogbo sílẹ̀ ni apákan, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti àgàbàgebè, àti ìlára, àti sísọ ọ̀rọ̀ buburú gbogbo Bí ọmọ ọwọ́ titun, kí ẹ máa fẹ́ wàrà ti Ẹ̀mí, èyí tí kò lẹ́tàn, kí ẹ̀yín lè máa tipasẹ̀ rẹ̀ dàgbà sí ìgbàlà nísinsìnyìí tí ẹ̀yín ti tọ́ ọ wò pé rere ni Olúwa Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti tọ̀ ọ́ wá, òkúta ààyè náà, èyí ti àwọn ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run yàn, òkúta iyebíye Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jésù Kírísítì Nítorí nínú ìwé mímọ́, ó wí pe Kìyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta ìgún-ilẹ̀ àṣàyàn, iyebíye, lélẹ̀ ni Síónì ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́ ojú kì yóò tì í Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́, Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, òun ni ó di pàtàkì ìgún-ilé, àti pẹ̀lú, Òkúta ìdìgbòlù, àti àpáta ìkọ̀sẹ̀ Nítorí wọn kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn Olu àlùfáà, Orílẹ̀ èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọla ń lá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn Ẹ̀yin tí kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹ̀yin tí kò rí àánú gbà rí, ṣùgbọ́n nísinsinyìí, ẹ ti rí àánú gbà Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo bẹ̀ yín, bí àlejò àti èrò, láti fà sẹ́hìn kúrò nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, tí ń ba ọkàn jagun Kí ìwà yín láàrin àwọn aláìkọlà dára pé, bí wọn ti ń sọ̀rọ̀ yín bí olùṣe búburú, nípa iṣẹ́ rere yín tí wọn ó máa kíyèsí, kí wọ́n lè máa yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ ti òun ba bẹ̀ wá wò Ẹ máa tẹríba fún gbogbo ìlànà ènìyàn nítorí ti Olúwa ì bá à ṣe fún ọba, fún olórí Tàbí fún àwọn baálẹ̀, fún àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ fún ìgbẹ̀san lára àwọn tí ń ṣe búburú, àti fún ìyìn àwọn tí ń ṣe rere Ìfẹ́ Ọlọ́run sá ni èyí pé, ní rere í ṣe, kí ẹ lè dẹ́kun ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan òmùgọ̀ ènìyàn Ẹ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni òmìnira, ṣùgbọ́n ẹ maṣe lo òmìnira yín láti bo ibi mọ́lẹ̀ ṣùgbọ́n kí ẹ gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ẹ bọ̀wọ̀ fún gbogbo ènìyàn, ẹ fẹ àwọn ará, ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ bọ̀wọ̀ fún ọba Ẹ̀yin ọmọ-ọdọ, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọ̀gá yín pẹ̀lú ìbẹ̀rù gbogbo, kì í ṣe fún àwọn ẹni rere àti oníwà tútù nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn òǹrorò pẹ̀lú Nítorí pé èyí ní ìgbóríyìn fún, bí ènìyàn bá fi oara da ìrora, ìjìyà lọ́nà àìtọ́, nítorí ọkàn rere sí Ọlọ́run Ṣùgbọ́n ògo kínni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba sẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, èyí ní ìgbóríyìn-fún lọ́dọ̀ Ọlọ́run Sí èyí ni a pè yín nítorí Kírísítì pẹ̀lú jìyà fún-un yin, ó fi àpẹẹrẹ sílẹ̀ fún-un yín, kí ẹ̀yin lè máa tọ ipaṣẹ̀ rẹ̀ Òun kò dẹ́ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni, a kò rí ẹ̀tàn kan lẹ́nu rẹ̀ Ẹni, nígbà tí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn nígbà tí ó jìyà tí kò sì halẹ̀ ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́ Ẹni tí òun tìkararẹ̀ fi ara rẹ̀ ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, pé kí àwa lè di òkú sí ẹ̀ṣẹ̀ ki a sì di ààyè sí òdodo nípa ìjìyà ẹni tí ó mú yín láradá Nítorí tí ẹ̀yin ń ṣáko lọ bí àgùntàn, ṣùgbọ́n nísinsinyìí ẹ̀yin ti padà sí ọ̀dọ̀ olùsọ́-àgùntàn àti bíṣọ́ọ̀bù ọkàn yín Àwọn Aya Àti Àwọn Ọkọ Àti aya Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín Kí ọ̀sọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀sọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀ Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó farasìn ní ọkàn, nínú ọ̀sọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbaànì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi sẹ ara wọn lọ́sọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ tiwọn Gẹ́gẹ́ bí Sárà ti gbọ́ ti Ábúráhámù, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀ Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi Òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogun ìbùkún Nítorí, Ẹni tí yóò bá fẹ ìyè, ti yóò sì rí ọjọ́ rere, kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi, àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀ Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn ṣùgbọ́n ojú Olúwa dojúkọ àwọn tí ń ṣe búburú Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, àlàáfíà ni ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kírísítì bí Olúwa ní ọkàn yín kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń bèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù Kí ẹ máa ni ẹ̀rí-ọkàn rere bi wọn ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kírísítì Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣiṣé búburú lọ Nítorí tí Kírísítì pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí Nínú èyí tí ó lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú Àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sáà kan ní ọjọ́ Nóà, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba àwọn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsìnyìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jésù Kírísítì Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹ́riba lábẹ́ rẹ̀ Ìgbé Ayé Fún Ọlọ́run Ǹjẹ́ bí Kírísítì ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run Nítorí ìgbà tí ó ti kọjá ti tó fún ṣíṣe ìfẹ́ àwọn aláìkọlà, rìnrìn nínú ìwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ọtí àmupara, ìréde òru, kíkó ẹ̀gbẹ́ ọ̀mùtí, àti ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ohun ìríra Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejú ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú Àwọn ẹni tí yóò jíyìn fún ẹni tí ó ti múra láti ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú Nítorí èyí ní a ṣá ṣe wàásù ìyìn rere fún àwọn òkú, kí a lè ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láàyè si Ọlọ́run nípa tí Ẹ̀mí Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo kù sí dẹ̀dẹ̀ nítorí náà kí ẹ̀yin wà ní àìrékọjá, kí ẹ sì máa sọra nínú àdúrà Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrin ara yín nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀ Ẹ máa ṣe ara yín ni àlejò láìsí ìkùnsínú Bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe ìpín fún ni rẹ̀ láàrin ara yín, bí ìríjú rere tí oníruúrú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́, kí í ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fifún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jésù Kírísítì, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrin yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábàápín ìyà Kírísítì, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kírísítì, ẹni ìbùkún ni yín nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí àpànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣé búburú, tàbí bí ẹni tí ń tọjúbọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí kírísítẹ́nì kí ojú má ṣe tì í ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo ní orúkọ yìí Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀hìn àwọn tí kò gba ìyìn rere Ọlọ́run yó ha ti rí Bí ó bá ṣe pé agbára káká ni a fi gba olódodo là, níbo ni aláìwà-bí-Ọlọ́run àti ẹlẹ́sẹ̀ yóò gbe yọjú sí Nítorí náà ẹ jẹ́ kí àwọn tí ń jìyà gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run máa ṣe rere, fi ọkàn wọn lè Ẹlẹ́dàá olóòtọ́ lọ́wọ́ Sí Àwọn Alàgbà Àti Àwọn Ọ̀dọ́kùnrin Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrin yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kírísítì, àti alábàápín nínú ògo tí a ó fihàn Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrin yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáse, bí kò se tìfẹ́tìfẹ́ kó má sì jẹ́ fún èrè ijẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìyè inú tí ó múra tan Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹni tí ń lo agbára lórí ìjọ, ṣùgbọ́n kí ẹ ṣe ara yín ní àpẹẹrẹ fún agbo Nígbà tí olórí Olùsọ́-àgùntàn bá sì fi ara hàn, ẹ̀yin ó gba adé ògo ti kì í ṣá Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tẹriba fún àwọn alàgbà Àní, gbogbo yín ẹ máa tẹriba fún ara yín kí ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara yin ní aṣọ nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga, ṣùgbọ́n ó ń fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákòókò Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín Ẹ máa wà ni àìrékọjá, ẹ máa ṣọ́ra nítorí Èṣù ọ̀ta yín, bí kínnìún tí ń ke ramúramù, o ń rìn káàkiri, ó ń wa ẹni tí yóò pajẹ Ẹ kọ ojú ìjà sí i pẹ̀lú ìdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ìyà kan-náà ni àwọn ará yín tí ń bẹ nínú ayé ń jẹ Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kírísítì Jésù, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkararẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀ Tírẹ̀ ni ògo àti agbára títí láé Nítorí Sílà, arákùnrin wa olóòtọ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti kà á sí, ni mo kọ̀wé kúkurú sí i yín, tí mo ń gbà yín níyànjú, tí mo sì ń jẹ́rìí pé, èyí ni òtítọ́ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ẹ dúró ṣinṣin nínú rẹ̀ Ìjọ tí ń bẹ ní Bábílónì, tí a yàn, pẹ̀lú kí yín, bẹ́ẹ̀ sì ni Máàkù ọmọ mi pẹ̀lú Ẹ fi ìfẹ́nukònú ìfẹ́ kí ara, yín Ìbí Sámúẹ́lì Ọkùnrin kan wà, láti Rámátaímù-Sófímù, láti ìlú olókè Éfúráímù, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elikánà, ọmọ Jéróhámù, ọmọ Élíhù, ọmọ Tóhù, ọmọ Súfù, ará Éfírátà Ó sì ní ìyàwó méjì orúkọ wọn ni Hánà àti Pẹ̀nínà Pẹ̀nínà ní ọmọ, ṣùgbọ́n Hánà kò ní Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí Olúwa alágbára jùlọ ní Ṣílò, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Hófínì àti Fínéhásì ti jẹ́ àlùfáà Olúwa Nígbàkígbà tí ó bá kan Elikánà láti ṣe ìrúbọ, òun yóò bù lára ẹran fún aya rẹ̀ Pẹ̀nínà àti fún gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin Ṣùgbọ́n ó máa ń pín ìlọ́po fun Hánà nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ àti pé Olúwa ti sé e nínú Nítorí pé Olúwa ti sé e nínú, orogún rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fín in níràn láti lè mú kí ó bínú Eléyìí sì máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọdọọdún Nígbàkígbà tí Hánà bá gòkè lọ sí ilé Olúwa , orogún rẹ̀ a máa fín-in níràn títí tí yóò fi máa sunkún tí kò sì ní lè jẹun Elikánà ọkọ rẹ̀ yóò sọ fún un pé, Hánà èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún Èéṣe tí ìwọ kò fi jẹun Èéṣe tí ìwọ fi ń ba ọkàn jẹ́ Èmi kò ha ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ bí Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n tún mu tán ní Ṣílò, Hánà dìde wá ṣíwájú Olúwa Nígbà náà, Élì àlùfáà wà lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa ní ibi tí ó máa ń jókòó Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn Hánà sunkún gidigidi, ó sì gbàdúrà sí Olúwa Ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ wí pé, Olúwa alágbára jùlọ tí ìwọ bá le bojú wo ìránṣẹ́-bìnrin rẹ kí ìwọ sì rántí rẹ̀, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ ṣùgbọ́n tí iwọ yóò fún un ní ọmọkùnrin, nígbà náà èmi yóò sì fi fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ a kì yóò sì fi abẹ kàn án ní orí Bí ó sì ṣe ń gbàdúrà sí Olúwa , Élì sì kíyèsí ẹnu rẹ̀ Hánà ń gbàdúrà láti inú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ètè rẹ̀ ni ó ń mì, a kò gbọ́ ohùn rẹ̀ Élì rò wí pé ó ti mu ọtí yó Ó sì wí fún un pé, Yóò ti pẹ́ fún ọ tó tí ìwọ yóò máa yó Mú ọtí wáìnì rẹ̀ kúrò Hánà dá a lóhùn pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi, Èmi ni obìnrin oníròbìnújẹ́ Èmi kò mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle Èmi ń tú ọkàn mi jáde sí Olúwa ni Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí obìnrin búburú Èmi ti ń gbàdúrà níhìn-ín nínú ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ mi Élì dáhùn pé, Má a lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi ohun tí ìwọ ti béèrè ní ọwọ́ rẹ̀ fún ọ Ó wí pé, Kí ìránṣẹ́-bìnrin rẹ rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ Bẹ́ẹ̀ ni ọbinrin náà bá tirẹ lọ, ó sì jẹun, kò sì fa ojú ro mọ́ Wọ́n sì díde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú Olúwa , wọn padà wa sí ilé wọn ni Rámà Elikánà si mọ aya rẹ̀ Olúwa sì rántì rẹ̀ Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìgbà tí Hánà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì, pé, Nítorí tí mo bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ Olúwa Ọkùnrin náà Elikánà, àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, gòkè lọ láti rúbọ ọdún sí Olúwa , àti láti sán ẹ̀jẹ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n Hánà kò gòkè lọ nítorí tí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, Ó di ìgbà tí mo bá gba ọmú lẹ́nu ọmọ náà, nígbà náà ni èmi yóò mú un lọ, kí òun lè fi ara hàn níwájú Olúwa , kí ó sí máa gbé ibẹ̀ títí láé Elikánà ọkọ rẹ̀ sì wí fún un pé, Ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ Dúró títí ìwọ yóò fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ ṣùgbọ́n kí Olúwa ṣáà mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà sì jókòó, ó sì fi ọmú fún ọmọ rẹ̀ títí ó fi gbà á lẹ́nu rẹ̀ Nígbà tí ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó sì mú un gòkè lọ pẹ̀lú ara rẹ̀ Pẹ̀lú ẹgbọrọ màlúù mẹ́ta, àti ìyẹ̀fun éfà kan, àti ìgò ọti-wáìnì kan, ó sì mú un wá sí ilé Olúwa ní Ṣílò ọmọ náà ṣì wà ní ọmọdé Wọ́n pa ẹgbọrọ màlúù, wọ́n sì mú ọmọ náà tọ Élì wá Hánà sì wí pé, Olúwa mi, bí ọkàn rẹ ti wà láàyè, Olúwa mi, èmi ni obìnrin náà tí ó dúró lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ níhìn-ín tí ń tọrọ lọ́dọ̀ Olúwa Ọmọ yìí ni mo ń tọrọ Olúwa sì fi ìdáhùn ìbéèrè tí mo béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ fún mi Nítorí náà pẹ̀lú, èmi fí i fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí tí mo ti béèrè rẹ̀ fún Olúwa Wọn si wólẹ̀ sin Olúwa nibẹ̀ A Fi Ṣọ́ọ̀lù Jẹ Ọba Sámúẹ́lì sì mú ìgò kékeré tí òróró wà nínú rẹ̀, ó sì dà á sí orí Ṣọ́ọ̀lù Ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, wí pé, Olúwa kò ha tí fi òróró yàn ọ ní olóri í lórí ohun ìní rẹ̀ Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rákélì ní Sélísà, ní agbégbé Bẹ́ńjámínì Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí Nísinsìn yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń damú nípa à rẹ Ó ń béèrè, Kí ni èmi yóò ṣe nípà ọmọ mi   Nígbà náà, ìwọ yóò lọ láti ibẹ̀ títí yóò fi dé ibi igi Tábórì ńlá Ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Bẹ́tẹ́lì yóò pàdé rẹ níbẹ̀ Ọ̀kan yóò mú ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta lọ́wọ́, èkejì, iṣù àkàrà mẹ́ta àti ẹ̀kẹtà yóò mú ìgò wáìnì Wọ́n yóò kí ọ, wọn yóò sì fún ọ ní ìṣù àkàrà méjì, tí ìwọ yóò gbà lọ́wọ́ ọ wọn Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò lọ sí òkè Ọlọ́run, níbi tí ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì wà Bí ìwọ ti ń súnmọ́ ìlú náà, ìwọ yóò bá àwọn wòlíì tí ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bọ̀ láti ibi gíga, pẹ̀lú líárì, támborí àti fèrè àti gìta níwájú wọn, wọn yóò sì máa sọ àṣọtẹ́lẹ̀ Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé ọ, nínú agbára, ìwọ yóò sì di ẹni ọ̀tọ̀ Bí ìwọ bá ti rí àmì wọ̀nyí, ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà láti ṣe, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ Lọ ṣáájú mi sí Gílgálì Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá láti rú ẹbọ sísun àti láti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ dúró fún ọjọ́ méje títí èmi yóò fi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti sọ fún ọ ohun tí ó yẹ tí ìwọ yóò ṣe Bí Ṣọ́ọ̀lù ti yípadà láti fi Sámúẹ́lì sílẹ̀, Ọlọ́run yí ọkàn Ṣọ́ọ̀lù padà àti pé gbogbo àmì wọ̀nyí sì wá sí ìmúṣẹ ní ọjọ́ náà Nígbà tí wọ́n dé òkè náà, àwọn wòlíì tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ pàdé rẹ̀, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e nínú agbára, ó sì darapọ̀ bá wọ́n sọ àṣọtẹ́lẹ̀ Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i tó ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì, wọ́n bi ara wọn, Kí ni ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kíṣì yìí Ṣé Ṣọ́ọ̀lù wà lára àwọn wòlíì ní Ọkùnrin kan tí ó ń gbé níbẹ̀ dáhùn pé, Ta ni baba wọn Ó ti di ohun tí a fi ń dáṣà pé, ǹjẹ́ Ṣọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn wòlíì bí Lẹ́yìn tí Ṣọ́ọ̀lù dákẹ́ sísọ àṣọtẹ́lẹ̀, ó lọ sí ibi gíga Nísinsìn yìí, arákùnrin baba Ṣọ́ọ̀lù béèrè lọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀lù àti ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Níbo ni ẹ lọ Ó wí pé, À ń wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ṣùgbọ́n nígbà tí a kò rí wọn, a lọ sí ọ̀dọ̀ Sámúẹ́lì Arákùnrin baba Ṣọ́ọ̀lù wí pé, Sọ fún mi ohun tí Sámúẹ́lì wí fún un yín Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, Ó fi dá wa lójú pé wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà Ṣùgbọ́n kò sọ fún arákùnrin baba a rẹ̀ ohun tí Sámúẹ́lì sọ nípa ọba jíjẹ Sámúẹ́lì pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ sí iwájú Olúwa ní Mísípà Ó sì wí fún wọn pé, Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ Èmi mú Ísírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Éjíbítì àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín Ẹ̀yin sì ti sọ pé, Rárá, yan ọba kan fún wa Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín Nígbà Sámúẹ́lì mú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì Ó kó ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣíwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Mátírì Ní ìparí a sì yan Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i, Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni Olúwa sì sọ pé, Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrin àwọn ẹrù Wọ́n sáré, wọ́n sì mú un jáde wá Bí ó ti dúró láàárin àwọn ènìyàn, ó sì ga ju gbogbo àwọn tí ó kù lọ láti èjìká rẹ̀ sókè Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí Olúwa ti yàn Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàárin gbogbo àwọn ènìyàn Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn! Sámúẹ́lì ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn àwọn ìlànà ìjọba Ó kọ wọ́n sínú ìwé, ó sì fi lélẹ̀ níwájú Olúwa Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì tú àwọn ènìyàn ká olúkúlùkù sí ilé e rẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù náà padà sí ilé e rẹ̀ ní Gíbíà Àwọn akọni ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wọ́n sì sìn ín Ṣùgbọ́n àwọn oníjàgbọ̀n kan wí pé, Báwo ni ẹni yìí yóò ṣe gbà wá Wọ́n kẹ́gan rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù fọwọ́ lẹ́rán Ṣọ́ọ̀lù Gba Ìlú Jábésì Sílẹ̀ Náhásì ará Ámónì gòkè lọ, ó sì dó ti Jabesi-Gílíádì, gbogbo ọkùnrin Jábésì sì wí fún Néhásì pé, Bá wa ṣe ìpinnú, àwa yóò sì máa sìn ọ́ Ṣùgbọ́n Náhásì ará Ámónì sì wí fún un pé, Nípa èyí ni èmi ó ò fi bá a yín ṣe ìpinnu, nípa yíyọ gbogbo ojú ọtún yín kúró, èmi o si fi yín se ẹlẹ́yà lójú gbogbo Ísírẹ́lì Àwọn àgbà Jábésì sì wí fún un pé, Fún wa ní ọjọ́ méje kí àwa lè rán oníṣẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti agbègbè bí ẹni kankan kò bá sì jáde láti gbà wá, àwa yóò fi ara wa fún ọ Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà sì wá sí Gíbíà tí ó jẹ́ ìlú Ṣọ́ọ̀lù, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, gbogbo wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún Nígbà náà gan an ni Ṣọ́ọ̀lù padà wá láti pápá, pẹ̀lú màlúù rẹ̀, ó sì béèrè pé, kín ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn Èéṣe tí wọ́n fi ń sunkún Nígbà náà ni wọ́n tún sọ fún wọn ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jábésì Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé e pẹ̀lú agbára, inú rẹ̀ sì ru sókè Ó sì mú màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì rán ẹyọyọ sí gbogbo Ísírẹ́lì nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ náà, ó ní i ẹ kéde pé, Èyí ni a ó ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tọ Ṣọ́ọ̀lù àti Sámúẹ́lì lẹ́yìn Nígbà náà ni ìbẹ̀rù Olúwa sì mú àwọn ènìyàn, wọ́n sì jáde bí ènìyàn kan ṣoṣo Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì kó wọn jọ ní Bésékì, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dógún àwọn ọkùnrin Júdà sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó wá pé, Sọ fún àwọn ọkùnrin Jabesi-Gílíádì pé, ní àkókò tí oòrùn bá mú lọ́la, àwa yóò gbà yín sílẹ̀ Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà lọ tí wọ́n sì sọ èyí fún àwọn ọkùnrin Jábésì, inú wọn sì dùn Wọ́n sọ fún àwọn ará Ámónì pé, Àwa yóò fi ara wa fún un yín ní ọ̀la, kí ẹ̀yin kí ó ṣe gbogbo èyí tí ó tọ́ lójú yín sí wa Ní ọjọ́ kejì Ṣọ́ọ̀lù pín àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí ipa mẹ́ta, wọ́n sì ya wọ àgọ́ àwọn ará Ámónì ní ìṣọ́ òwúrọ̀, wọ́n sì pa wọ́n títí di ìmóju ọjọ́ Àwọn tó kù wọ́n sì fọ́nká, tó bẹ́ẹ̀ tí méjì wọn kò kù sí ibìkan Àwọn ènìyàn sọ fún Sámúẹ́lì pé, Ta ni ó béèrè wí pé, Ṣọ́ọ̀lù yóò ha jọba lórí wa Mú àwọn ọkùnrin náà wá, a ó sì pa wọ́n Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù wí pé, A kì yóò pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí lónìí yìí ni Olúwa gba Ísírẹ́lì là Nígbà náà ni Sámúẹ́lì wí fún àwọn ènìyàn pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Gílígálì, kí a lè fi ẹṣẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù múlẹ̀ bí ọba Nítorí náà gbogbo ènìyàn lọ sí Gílígálì, wọn sí fí Ṣọ́ọ̀lù jọba ní ìwájú Olúwa Níbẹ̀, ni wọn ti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ní ìwájú Olúwa , Ṣọ́ọ̀lù àti gbogbo Ísírẹ́lì ṣe àjọyọ̀ ńlà Ọ̀rọ̀ Àlàáfíà Samúẹ́lì Sámúẹ́lì sì wí fún gbogbo Ísírẹ́lì pé, Èmi tí gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ sọ fún mi, èmi sì ti yan ọba fún un yín Nísinsìn yìí ẹ ti ní ọba bí olórí yín Bí ó ṣe tèmi, èmi ti di arúgbó, mo sì ti hewú, àwọn ọmọ mi sì ń bẹ níhìn yìí pẹ̀lú yín Èmi ti ń ṣe olórí yín láti ìgbà èwe mi wá títí di òní yìí Èmi dúró níhìn yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni àmì òróró rẹ̀ Màlúù ta ni mo gbà rí Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí Ta ni mo rẹ́ jẹ rí Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi ti ara mi lójú Bí mo bá ti ṣe ìkankan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún un yín Wọ́n sì dáhùn wí pé, Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan Samúẹ́lì sì wí fún wọn pé, Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi Wọ́n sì sọ wí pé, Òun ni ẹlẹ́rìí Nígbà náà ni Sámúẹ́lì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, Olúwa ni ó yan Mósè àti Árónì àti ti ó mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti Éjíbítì Nísinsin yìí, ẹ dúró níbi, nítorí èmi ń lọ láti bá a yín sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa ní ti gbogbo ìṣe òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe fún un yín àti fún àwọn baba yín Lẹ́yìn ìgbà tí Jákọ́bù wọ Éjíbítì, wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa sì rán Mósè àti Árónì, tí wọ́n mú àwọn baba ńlá yín jáde láti Éjíbítì láti mú wọn jókòó níbí yìí Ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tà wọ́n sí ọwọ́ àwọn Sísérà, olórí ogun Hásórì, àti sí ọwọ́ àwọn Fílístínì àti sí ọwọ́ ọba Móábù, tí ó bá wọn jà Wọ́n kégbe pe Olúwa , wọ́n sì wí pé, Àwa ti ṣẹ̀ a ti kọ Olúwa sílẹ̀, a sì ti sin Báálì, àti Ásítarótì Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, àwa yóò sì sìn ọ́ Nígbà náà ni Olúwa rán Jérúbù-Báálì, Bárákì, Jẹ́fítà àti Sámúẹ́lì, ó sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a yín gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń gbé ní àlàáfíà Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin sì rí i pé Náhásì ọba àwọn Ámónì dìde sí i yín, ẹ sọ fún mi pé, Rárá, àwa ń fẹ́ ọba tí yóò jẹ́ lórí wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ ọba yín Nísinsìn yìí èyí ni ọba tí ẹ̀yin ti yàn, tí ẹ̀yin béèrè fún wò ó, Olúwa ti fi ọba jẹ lórí yín Bí ẹ̀yin bá bẹ̀rù Olúwa àti bí ẹ̀yin bá ń sìn ín, tí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ̀yin kò sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, àti tí ẹ̀yin àti ọba tí ó jẹ lórí yín bá ń tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín ó dára ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gbọ́ tí Olúwa , tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára yín sí ibi, bí ó ti wà lára baba yín Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì wo ohun ńlá yìí tí Olúwa fẹ́ ṣe ní ojú u yín! Òní kì í ha á ṣe ọjọ́ ìkórè ọkà àlìkámà bí Èmi yóò ké pe Olúwa kí ó rán àrá àti òjò Ẹ̀yin yóò sì mọ irú ohun búburú tí ẹ ti ṣe níwájú Olúwa nígbà tí ẹ̀ ń béèrè fún ọba Nígbà náà ni Sámúẹ́lì ké pe Olúwa , Olúwa sì rán ààrá àti òjò ní ọjọ́ náà Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa àti Sámúẹ́lì púpọ̀ Gbogbo àwọn ènìyàn sì wí fún Sámúẹ́lì pé, Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ kí a má ba à kú, nítorí tí àwa ti fi búburú yìí kún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní bí béèrè fún ọba Sámúẹ́lì sì dá wọn lóhùn pé, Ẹ má bẹ̀rù, ẹ ti ṣe gbogbo búburú yìí ṣíbẹ̀ ẹ má ṣe yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa , ṣùgbọ́n ẹ fi gbogbo àyà yín sin Olúwa Ẹ má ṣe yípadà sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà Wọn kò le ṣe ohun rere kan fún un yín, tàbí kí wọ́n gbà yín là, nítorí asán ni wọ́n Nítorí orúkọ ńlá rẹ̀ Olúwa kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, nítorí tí inú Olúwa dùn láti fi yín ṣe ènìyàn rẹ̀ Bí ó ṣe ti èmi ni, kí á má rí i pé èmi dẹ̀ṣẹ̀ sí Olúwa nípa dídẹ́kun àti gbàdúrà fún un yín Èmi yóò sì kọ́ ọ yín ní ọ̀nà rere àti ọ̀nà òtítọ́ Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé, ẹ bẹ̀rù Olúwa , kí ẹ sì sìn ín nínú òtítọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an yín Ẹ kíyèsí ohun ńlá tí ó ti ṣe fún un yín Ṣíbẹ̀ bí ẹ̀yin bá ń ṣe búburú, ẹ̀yin àti ọba yín ni a ó gbá kúrò Sámúẹ́lì fi Ṣọ́ọ̀lù bú Ṣọ́ọ̀lù sì jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jọba, ó sì jọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún méjìlélógójì Ṣọ́ọ̀lù yan ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkùnrin ní Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún méjì sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Míkimásì àti ní ìlú òkè Bẹ́tẹ́lì ẹgbẹ̀rún kan sì wà lọ́dọ̀ Jónátanì ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn Jónátánì sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì ní Gébà, Fílístínì sì gbọ́ èyí Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, Jẹ́ kí àwọn Hébérù gbọ́! Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ ìròyìn pé, Ṣọ́ọ̀lù ti kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì, Ísírẹ́lì sì di òórùn búburú fún àwọn Fílístínì Àwọn ènìyàn náà sì péjọ láti dara pọ̀ mọ́ Ṣọ́ọ̀lù ní Gílígálì Àwọn Fílístínì kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Ísírẹ́lì jà, pẹ̀lú ẹgbàá-mẹ́ẹ̀dógún kẹ̀kẹ́, ẹgbẹ̀ta ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí òkun Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Míkímásì ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Bẹti-Áfénì Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàárin àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kàǹga gbígbẹ Àwọn Hébérù mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jọ́dánì sí ilẹ̀ Gádì àti Gílíádì Ṣọ́ọ̀lù wà ní Gílígálì ṣíbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù Ó sì dúró di ọjọ́ méje, àkókò tí Sámúẹ́lì dá ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì kò wá sí Gílígálì, àwọn ènìyàn Ṣọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí ní túká Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, Ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi, Ṣọ́ọ̀lù sì rú ẹbọ sísun náà Bí ó sì ti ń parí rírú ẹbọ náà, Sámúẹ́lì sì dé, Ṣọ́ọ̀lù sì jáde láti lọ kí i Sámúẹ́lì sì wí pé, Kí ni ìwọ ṣe yìí Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Fílístínì sì kó ara wọ́n jọ ní Míkímásì, mo rò pé, Àwọn Fílístínì yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gílígálì nísinsìn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere Olúwa Báyìí ni mo mú ara mi ní ipa láti rú ẹbọ sísun náà Sámúẹ́lì sì wí fún un pé, Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́ bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Ísírẹ́lì láéláé Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, Olúwa ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin Olúwa mọ́ Nígbà náà ni Sámúẹ́lì kúrò ní Gílígálì, ó sì gòkè lọ sí Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì, Ṣọ́ọ̀lù sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ ọ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ Jónátanì àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú wọn dúró ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì, nígbà tí àwọn Fílístínì dó ní Míkímásì Ẹgbẹ́ àwọn onísùmọ̀mí mẹ́ta jáde lọ ní àgọ́ àwọn Fílístínì ní ọnà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Ẹgbẹ́ kan gba ọ̀nà ti Ófírà ní agbégbé ìlú Ṣúálì Òmíràn gba ọ̀nà Bẹti-Hórónì, ẹ̀kẹ́ta sí ìhà ibodè tí ó kọjú sí àfonífojì Ṣébóímù tí ó kọjú sí ijù A kò sì rí alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí tí àwọn Fílístínì wí pé, Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn Hébérù yóò rọ idà tàbí ọ̀kọ̀! Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Ísírẹ́lì tọ àwọn Fílístínì lọ láti pọ́n dòjé wọn, ọ̀kọ̀, àáké àti ọ̀ṣọ̀ wọn Iye tí wọ́n fi pọ́n dòjé àti ọ̀kọ̀ jẹ́ ọwọ́ méjì nínú ìdásímẹ́ta ṣékélì, àti ìdásímẹ́ta ṣékélì fún pípọ́n ọ̀yà-irin tí ilẹ̀, àáké àti irin ọ̀pá olùṣọ́ màlúù Bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ìjà ẹnìkankan nínú àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì kò sì ní idà, tàbí ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ àfi Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ Jónátanì ni wọ́n ni wọ́n Àwọn ẹgbẹ́ ogun Fílístínì sì ti jáde lọ sí ìkọjá Míkímásì Jónátanì Kọlu Àwọn Fílístínì Ní ọjọ́ kan, Jónátanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, Wá, jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìlú olódi àwọn Fílístínì tí ó wà ní ìhà kejì Ṣùgbọ́n kò sọ fún baba rẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù sì dúró ní ìhà etí ìpínlẹ̀ Gíbéà lábẹ́ igi pòmégánétè èyí tí ó wà ní Mígírónù Àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀, lára wọn ni Áhíjà, tí ó wọ Éfódù Òun ni ọmọ arákùnrin Íkábódù Áhítúbì, ọmọ Fínéhásì, ọmọ Élì, àlùfáà Olúwa ní Ṣílò kò sí ẹni tí ó mọ̀ pé Jónátanì ti lọ Ní ọ̀nà tí Jónátanì ti ń fẹ́ láti kọjá dé ìlú olódi àwọn Fílístínì, ní bèbè òkúta mímú kan wá, orúkọ èkíní sì ń jẹ́ Bóṣéṣì, orúkọ èkejì sì ń jẹ́ Sénè Bèbè òkúta kan dúró sí àríwá ní ìhà Míkímásì, èkejì sì wà ní gúsù ní ìhà Gíbéà Jónátanì sì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, Wá, jẹ́ kí a lọ sí ìlu olódi àwọn aláìkọlà yìí Bóyá Olúwa yóò jà fún wa, kò sí ohun tó lè di Olúwa lọ́wọ́ láti gbàlà, yálà nípaṣẹ̀ púpọ̀ tàbí nípaṣẹ̀ díẹ̀ Ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì wí pé, Ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ, tẹ̀ṣíwájú Èmi wà pẹ̀lú ọkàn àti ẹ̀mí rẹ Jónátanì sì wí pé, Wá nígbà náà, àwa yóò rékọjá sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin wọ̀nyí, kí a sì jẹ́ kí wọ́n rí wa Bí wọ́n bá sọ fún wa pé, Ẹ dúró títí àwa yóò fi tọ̀ yín wá, àwa yóò dúró síbi tí a wà, àwa kì yóò sì gòkè tọ̀ wọ́n lọ Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá wí pé, Ẹ gòkè tọ̀ wá wá, àwa yóò gòkè lọ, nítorí èyí ni yóò jẹ́ àmì fún wa pé Olúwa ti fi wọ́n lé wa lọ́wọ́ Báyìí ní àwọn méjèèjì sì fi ara wọn hàn fún ìlú olódi Fílístínì Àwọn Fílístínì sì wí pé, Wò ó! Àwọn Hébérù ń fà jáde wá láti inú ihò tí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sí Àwọn ọkùnrin ìlú olódi náà sì kígbe sí Jónátánì àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, Ẹ gòkè tọ̀ wá wá àwa yóò sì kọ́ ọ yín ní ẹ̀kọ́ Jónátánì sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, Gòkè tọ̀ mí lẹ́yìn Olúwa ti fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ Jónátánì lo ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ láti fà gòkè pẹ̀lú ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ Àwọn Fílístínì sì ṣubú níwájú Jónátánì ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì tẹ̀lé e, ó sì ń pa lẹ́gbẹ̀ ẹ́ rẹ̀ Ní ìkọlù èkíní yìí, Jónátanì àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì pa ogún ọkùnrin ní agbégbé tó tó ìwọ̀n ààbọ̀ sarè ilẹ̀ Nígbà náà ni ìbẹ̀rù bojo bá àwọn ọmọ ogun àwọn tí ó wà ní ibùdó àti ní pápá, àti àwọn tí ó wà ní ilé ìlú olódi àti àwọn tí ń kó ìkógun, ilẹ̀ sì mì Ó jẹ́ ìbẹ̀rù tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá Àwọn tí ó ń ṣọ́nà fún Sàúlù ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì sì rí àwọn ọmọ ogun ń túká ní gbogbo ọ̀nà Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, Ẹ ka àwọn ènìyàn kí ẹ sì mọ ẹni tí ó jáde kúrò nínú wa Nígbà tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, sì wòó, Jónátanì àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ni kò sì sí níbẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Áhíjà pé, Gbé àpótí Ọlọ́run wá Àpótí Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìgbà náà Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì ń bá àlùfáà sọ̀rọ̀, ariwo ní ibùdó àwọn Fílístínì sì ń pọ̀ ṣíwájú sí Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún àlùfáà pé, Dá ọwọ́ rẹ dúró Ṣọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ sì péjọ, wọ́n sì lọ sí ojú ìjà Wọ́n sì bá gbogbo àwọn Fílístínì ní ìdàrúdàpọ̀ ńlá, idà olúkúlùkù sì wà lára ọmọ ẹnìkéjì rẹ̀ Àwọn Hébérù tí ó ti wà lọ́dọ̀ àwọn Fílístínì tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti gòkè tẹ̀lé wọn lọ sí àgọ́ wọn wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ti wà pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì Nígbà tí gbogbo àwọn Ísírẹ́lì tí ó ti pa ara wọn mọ́ nínú òkè ńlá Éfúráímù gbọ́ pé àwọn Fílístínì sá, wọ́n darapọ̀ mọ́ ìjà náà ní ìlépa gbígbóná Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì gba Ísírẹ́lì ní ọjọ́ náà, ìjà náà sì rékọjá sí Bẹti-Áfénì Gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wà ní ìpọ́njú ńlá ní ọjọ́ náà, nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù ti fi àwọn ènìyàn gégùn ún wí pé, Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ títí di alẹ́, títí èmi yóò fi gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀ta mi! Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkankan nínú ọ̀wọ́ ogun náà tí ó fi ẹnu kan oúnjẹ Gbogbo àwọn ènìyàn sì wọ inú igbó, oyin sì wà lórí ilẹ̀ náà Nígbà tí wọ́n dé inú igbó náà, wọ́n sì rí oyin ń sun jáde, kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ kan ẹnu rẹ̀ ṣíbẹ̀, nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìfiré Ṣùgbọ́n Jónátanì kò gbọ́ pé baba rẹ̀ ti fi ègún kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ orí ọ̀pá tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bọ afárá oyin náà, ó sì fi sí ẹnu rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dán Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun sọ fún un pé, Baba rẹ fi ègún kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ogun wí pé, Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ ní òní! Ìdí nìyìí tí àárẹ̀ fi mú àwọn ènìyàn Jónátánì sì wí pé, Baba mi ti mú ìdàámú bá ìlú, wò ó bí ojú mi ti dán nígbà tí mo fi ẹnu kan oyin yìí Báwo ni kò bá ti dára tó bí àwọn ènìyàn bá ti jẹ nínú ìkógun àwọn ọ̀ta wọn lónìí, pípa àwọn Fílístínì ìbá ti pọ̀ tó Ní ọjọ́ náà, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pa nínú àwọn Fílístínì láti Míkímásì dé Áíjálónì, ó sì rẹ àwọn ènìyàn náà Wọ́n sáré sí ìkógun náà, wọ́n sì mú àgùntàn Màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n sórí ilẹ̀, wọ́n sì jẹ wọ́n papọ̀ tẹ̀jẹ́tẹ̀jẹ̀ Nígbà náà ni ẹnìkan sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Wò ó, àwọn ènìyàn tí ń dẹ́sẹ̀ sí Olúwa nípa jíjẹ ẹrán tí ó ní ẹ̀jẹ̀ lára Ó sì wí pé, Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti pọ̀jù, yí òkúta ńlá síbi nísinsìn yìí Nígbà náà ni ó wí pé, Ẹ jáde lọ sáàrín àwọn ènìyàn náà kí ẹ sì wí fún wọn pé, Kí olúkúlùkù wọn mú màlúù àti àgùntàn tirẹ̀ tọ̀ mí wá, kí wọ́n sì pa wọ́n níhìn, kí wọ́n sì jẹ́ Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí Olúwa , kí ẹ má ṣe jẹ ẹran tòun tẹ̀jẹ̀   Bẹ́ẹ̀ ní olúkúlùkù mú màlúù tirẹ̀ wá ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀ Nígbà náà Ṣọ́ọ̀lù kọ́ pẹpẹ kan fún Olúwa èyí sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe èyí Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, Ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ tọ Fílístínì lọ ní òru, kí a bá wọn jà títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, kí a má sìṣe dá ẹnìkankan sí nínú wọn Wọ́n sì wí pé, Ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ̀ Ṣùgbọ́n àlùfáà wí pé, Ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọ́run níhìn ín Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé, Ṣé kí n sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn Fílístínì lọ bí Ǹjẹ́ ìwọ yóò fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ bí Ṣùgbọ́n Olúwa kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, Ẹ wá síhìn ín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olórí ogun, kí a ṣe ìwádìí irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti ṣẹ̀ lónìí Bí Olúwa tí ó gba Ísírẹ́lì là ti wà, bí ó bá ṣe pé a rí í lára Jónátanì ọmọ mi, ó ní láti kú Ṣùgbọ́n ẹnìkankan nínú wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, Ẹ lọ sí apá kan èmi àti Jónátanì ọmọ mi yóò lọ sí apá kan Gbogbo àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, Ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú rẹ Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì pé, Fún mi ní ìdáhùn tí ó tọ́ A sì mú Jónátanì àti Ṣọ́ọ̀lù nípa ìbò dídì, àwọn ènìyàn náà sì yege Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, Ẹ dìbò láàárin èmi àti Jónátanì ọmọ mi Ìbò náà sì mú Jónátanì Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Jónátanì pé, Sọ nǹkan tí ìwọ ṣe fún mi Jónátanì sì sọ fún un pé, Mo kàn fi orí ọ̀pá mi tọ́ oyin díẹ̀ wò Nísinsìn yìí ṣé mo ní láti kú Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, Kí Olúwa kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ sí mi, bí ìwọ kò bá kú Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Ǹjẹ́ ó yẹ kí Jónátanì kú, ẹni tí ó ti mú ìgbàlà ńlá yìí wá fún Ísírẹ́lì Kí a má rí í! Bí Olúwa ti wà, ọ̀kan nínú irun orí rẹ̀ kì yóò bọ́ sílẹ̀, nítorí tí ó ṣe èyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Báyìí ni àwọn ènìyàn gba Jónátanì sílẹ̀, kò sì kú Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù sì dẹ́kun lílépa àwọn Fílístínì, àwọn Fílístínì sì padà sí ìlú wọn Lẹ́yìn ìgbà tí Ṣọ́ọ̀lù ti jọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì bá gbogbo ọ̀tá wọn jà yíká Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì Édómù, àti àwọn ọba Ṣọ́bà, àti àwọn Fílístínì Ibikíbi tí ó bá kọjú sí, ó máa ń fi ìyà jẹ wọ́n Ó sì jà tagbáratagbára, ó ṣẹ́gun àwọn Ámálékì, ó sì ń gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ń kọlù wọ́n Àwọn ọmọ Sọ́ọ̀lù sì ni Jónátánì, Ísúì àti Málíkísúà Orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà sì ni Mérábù àti orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ni Míkálì Orúkọ ìyàwó rẹ̀ ní Áhínóámù ọmọbìnrin Áhímásì Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Ábínérì ọmọ Nérì arákùnrin baba Sọ́ọ̀lù Kíṣì baba Ṣọ́ọ̀lù àti Ábínérì baba Nérì sì jẹ́ ọmọ Ábíélì Ní gbogbo ọjọ́ Ṣọ́ọ̀lù, ogun náà sì gbóná sí àwọn Fílístínì, níbikíbi tí Ṣọ́ọ̀lù bá sì ti rí alágbára tàbí akíkanjú ọkùnrin, a sì mú u láti máa bá a ṣiṣẹ́ Sámúẹ́lì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Èmi ni Olúwa rán láti fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì fetí sílẹ̀ láti gbọ́ Iṣẹ́ tí Olúwa rán mi sí ọ́ Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára wí Èmi yóò jẹ àwọn Ámálékì níyà fún ohun tí wọ́n ti ṣe sí Ísírẹ́lì nígbà tí wọn dè wọn lọ́nà nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Éjíbítì Lọ nísinsìn yìí, kí o sì kọlu Ámálékì, kí o sì pa gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ ti wọn ní àparun Má ṣe dá wọn sí, pa ọkùnrin àti obìnrin wọn, ọmọ kékeré àti ọmọ ọmú, màlúù àti àgùntàn, ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn Bẹ́ẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù kó àwọn ènìyàn jọ, ó sì ka iye wọn ní Táláémù, wọ́n sì jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ àwọn ológun ẹlẹ́ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹgbàárún àwọn ọkùnrin Júdà Ṣọ́ọ̀lù sì lọ sí ìlú Ámálékì ó sì gọ dè wọ́n ní àfonífojì kan Nígbà náà ni ó wí fún àwọn Kénáítì pé, Ẹ lọ, kúrò ní Ámálékì kí èmi má ba à run yín pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀yin fi àánú hàn fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n gòkè ti Éjíbítì wá Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Kénáítì lọ kúrò láàrin àwọn Ámálékì Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù kọlu àwọn Ámálékì láti Háfílà dé Súrì, tí ó fi dé ìlà oòrùn Éjíbítì Ó sì mú Ágágì ọba Ámálékì láàyè, ó sì fi idà rẹ̀ kọlu gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dá Ágágì sí àti èyí tí ó dára jùlọ nínú àgùntàn àti màlúù àti ọ̀dọ́ àgùntàn àbọ́pa àti gbogbo nǹkan tó dára Wọ́n kò sì fẹ́ pa àwọn wọ̀nyí run pátapáta ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan tí kò dára tí kò sì ní láárí ni wọ́n parun pátapáta Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Sámúẹ́lì wá pé Èmi káànú gidigidi pé mo fi Ṣọ́ọ̀lù jọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́ Inú Sámúẹ́lì sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì képe Olúwa ní gbogbo òru náà Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Sámúẹ́lì sì dìde láti lọ pàdé Ṣọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún un pé, Ṣọ́ọ̀lù ti wá sí Kámẹ́lì Ó ti kọ́ ibìkan fún ara rẹ̀ níbẹ̀, ó sì ti yípadà, ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Gílígálì Nígbà tí Sámúẹ́lì sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún un pé, Olúwa bùkún fún ọ, mo ti ṣe ohun tí Olúwa pa láṣẹ Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, Èwo wá ni igbe àgùntàn tí mo ń gbọ́ ní etí mi Kí ni igbe màlúù ti mo ń gbọ́ yìí Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, Àwọn ọmọ ogun ní o mú wọn láti Ámálékì wá, wọ́n dá àwọn àgùntàn, àti màlúù tí ó dára jùlọ sí láti fi rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n a pa àwọn tó kù run pátapáta Sámúẹ́lì sí wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Dákẹ́ ná, jẹ́ kí èmi kí ó sọ ohun tí Olúwa wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ Sọ́ọ̀lù sì wí pé, Sọ fún mi Sámúẹ́lì sì wí pé, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ fi ìgbà kan kéré lójú ara rẹ, ǹjẹ́ ìwọ kò ha di olórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì Olúwa fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì Ó sì rán ọ níṣẹ́ wí pé, Lọ, kí o sì pa àwọn ènìyàn búburú ará Ámálékì run pátapáta gbógun tì wọ́n títí ìwọ yóò fi run wọ́n Èéṣe tí ìwọ kò fi gbọ́ ti Olúwa Èéṣe tí ìwọ fi sáré sí ìkógun tí o sì ṣe búburú níwájú Olúwa Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Sámúẹ́lì pé, Ṣùgbọ́n èmi ti ṣe ìgbọ́rán sí Olúwa , èmi sì ti lọ ní ọ̀nà tí Olúwa rán mi Mo sì ti pa àwọn ará Ámálékì run pátapáta, mo sì ti mú Ágágì ọba wọn padà wá Àwọn ọmọ ogun ti mú àgùntàn àti màlúù lára ìkógùn èyí tí ó dára láti fi fún Olúwa láti fi rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Gílígálì Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì dáhùn pé, Ǹjẹ́ Olúwa ní inú dídùn sí ọrẹ sísun àti ẹbọ ju kí a ṣe ohun tí Olúwa wí Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ, àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa , Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún Sámúẹ́lì pé, Èmi ti ṣẹ̀ Mo ti rú òfin Olúwa àti ọ̀rọ̀ rẹ̀ Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́ Mo bẹ̀ ọ́ nísinsìn yìí, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn, kí ó sì yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè sin Olúwa Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí fún un pé, Èmi kò ní bá ọ padà Ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa sílẹ̀, Olúwa sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì! Bí Sámúẹ́lì sì ti fẹ́ yípadà láti lọ, Ṣọ́ọ̀lù sì di ẹ̀wù ìlekè rẹ̀ mú, ó sì fàya Sámúẹ́lì sì wí fún un pé, Olúwa ti fa ìjọba Ísírẹ́lì ya kúrò lọ́wọ́ ọ̀ rẹ lónìí, ó sì ti fi fún aládùúgbò rẹ kan tí ó sàn jù ọ́ lọ Ẹni tí ó ń ṣe ògo Ísírẹ́lì, kì í purọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í yí ọkàn rẹ̀ padà nítorí kì í ṣe ènìyàn tí yóò yí ọkàn rẹ̀ padà Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, Èmi ti ṣẹ̀, ṣùgbọ́n jọ̀wọ́ bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbààgbà ènìyàn mi, àti níwájú u Ísírẹ́lì, yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè tẹríba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ Bẹ́ẹ̀ ni Sámúẹ́lì sì yípadà pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì sin Olúwa Nígbà náà ni Sámúẹ́lì wí pé, Mú Ágágì ọba àwọn ará Ámálékì wá fún mi Ágágì sì tọ̀ ọ́ wá ní ìgboyà pẹ̀lú èrò pé, Nítòótọ́ ìkorò ikú ti kọjá Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, Bí idà rẹ ti sọ àwọn obìnrin di aláìní ọmọ bẹ́ẹ̀ ni ìyá rẹ yóò sì di aláìní ọmọ láàárin obìnrin Sámúẹ́lì sì pa Ágágì níwájú Olúwa ni Gílígálì Nígbà náà ni Sámúẹ́lì lọ sí Rámà, Ṣọ́ọ̀lù sì gòkè lọ sí ilé e rẹ̀ ní Gíbéà tí Ṣọ́ọ̀lù Sámúẹ́lì kò sì padà wá mọ́ láti wo Ṣọ́ọ̀lù títí ó fi di ọjọ́ ikú u rẹ̀, ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì káànú fún Ṣọ́ọ̀lù Ó sì dun Olúwa pé ó fi Ṣọ́ọ̀lù jọba lórí Ísírẹ́lì Sámúẹ́lì Fi Òróró Yan Dáfídì Olúwa sọ fún Sámúẹ́lì pé, Yóò ha ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa dárò Ṣọ́ọ̀lù, nígbà tí ó jẹ́ pé mo ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì Rọ òróró kún inú ìwo rẹ, kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, Èmi rán ọ sí Jésè ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Èmi ti yan ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ ọba Sùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé Báwo ni èmi yóò ṣe lọ Bí Ṣọ́ọ̀lù bá gbọ́ nípa rẹ̀, yóò pa mi Olúwa wí pé, Mú abo ẹgbọ̀rọ̀ màlúù kan pẹ̀lú rẹ, kí o sì wí pé, Èmi wá láti wá rúbọ sí Olúwa Pe Jésè wá sí ibi ìrúbọ náà, Èmi yóò sì fi ohun tí ìwọ yóò ṣe hàn ọ́ Ìwọ yóò fi òróró yàn fún mi, ẹni tí èmi bá fi hàn ọ́ Sámúẹ́lì ṣe ohun tí Olúwa sọ Nígbà tí ó dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àyà gbogbo àgbààgbà ìlú já, nígbà tí wọ́n pàdé rẹ̀ Wọ́n béèrè pé, Ṣé àlàáfíà ní ìwọ bá wá Sámúẹ́lì sì dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà ni mo wá láti wá rúbọ sí Olúwa Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì wá rúbọ pẹ̀lú ù mi Nígbà náà ni ó sì ya Jésè sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì pè wọ́n wá sí ibi ìrúbọ náà Nígbà tí wọ́n dé, Sámúẹ́lì rí Élíábù, ó rò nínú ara rẹ̀ pé lóòótọ́ ẹni òróró Olúwa dúró níbí níwájú Olúwa Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Sámúẹ́lì pé, Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Olúwa kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n Olúwa máa ń wo ọkàn Nígbà náà ni Jésè pe Ábínádábù, ó sì jẹ́ kí ó rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, Olúwa kò yan ẹni yìí Jésè sì jẹ́ kí Sámà rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì, ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, Olúwa kò yan ẹni yìí náà Jésè jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ méje rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì sọ fún un pé, Olúwa kò yan àwọn wọ̀nyí Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jésè pé, Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ Jésè dáhùn pé, Ó ku àbíkẹ́yìn wọn, ó ń tọ́jú agbo àgùntàn Sámúẹ́lì sì wí pé, Rán ìránṣẹ́ lọ pè é wá àwa kò ní jókòó títí òun yóò fi dé Ó sì ráńṣẹ́ sí i, wọ́n sì mú un wọlé wá, ó jẹ́ ẹni tó mọ́ra, àwọ̀ ara rẹ̀ dùn ún wò, ó jẹ́ arẹwà gidigidi Nígbà náà ni Olúwa wí pé, Dìde kí o sì fi òroró yàn án, òun ni ẹni náà Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú ìwo òróró, ó sì ta á sí i ní orí ní iwájú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, láti ọjọ́ náà lọ, Ẹ̀mi mímọ́ Olúwa wá sí orí Dáfídì nínú agbára Sámúẹ́lì sì lọ sí Rámà Nísinsìn yìí, ẹ̀mi Olúwa ti kúrò lára Ṣọ́ọ̀lù, ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa sì ń yọ ọ́ lẹ́nu Àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún un pé, Wò ó, ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń yọ ọ́ lẹ́nu Jẹ́ kí Olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà níhìn ín láti wa ẹnìkan tí ó lè fi dùùrù kọrin Yóò sì ṣe é nígbà tí ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá bà lé ọ, ìwọ yóò sì sàn Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ wá ẹnìkan tí ó lè kọrin dáradára kí ẹ sì mú u wá fún mi Ọ̀kan nínú ìránṣẹ́ náà dáhùn pé, Èmi ti ri ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Jésè ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó mọ orin kọ, ó jẹ́ alágbára àti ológun Ó ní ọgbọ́n ọ̀rọ̀ òun sì dára ní wíwò Olúwa sì wà pẹ̀lú u rẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù sì rán oníṣẹ́ sí Jésè wí pé, Rán Dáfídì ọmọ rẹ sí mi, ẹni tí ó ń ṣọ́ àgùntàn Jésè sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti a di ẹrù lé àti ìgò ọtí wáìnì àti ọmọ ewúrẹ́ ó sì rán wọn nípa ọwọ́ ọ Dáfídì ọmọ rẹ̀ sí Ṣọ́ọ̀lù Dáfídì sì tọ Ṣọ́ọ̀lù lọ, ó sì dúró níwájú rẹ̀ òun sì fẹ́ ẹ gidigidi, Dáfídì sì wá di ẹni tí ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù ránṣẹ́ sí Jésè, pé, Jẹ́ kí Dáfídì dúró níwájú mi, nítorí tí ó wù mí Ó sì ṣe, nígbà tí ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá bá dé sí Ṣọ́ọ̀lù, Dáfídì a sì fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lára dùùrù a sì san fún Ṣọ́ọ̀lù, ara rẹ̀ a sì dá ẹ̀mi búburú náà a sì fi sílẹ̀ Dáfídì Àti Gòláyátì Fílístínì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ fún ogun ní Síkọ̀ ti Júdà Wọ́n pàgọ́ sí Efesidámímù, láàárin Síkọ̀ àti Ásékà, Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ́n kò ara wọ́n jọ pọ̀, wọ́n sì pàgọ́ ní àfonífojì ní Élà wọ́n sì gbé ogun wọn sókè ní ọ̀nà láti pàdé àwọn Fílístínì Àwọn Fílístínì sì wà ní orí òkè kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì wà ní orí òkè mìíràn, àfonífojì sì wà láàrin wọn Ọ̀gágun tí a ń pè ní Gòláyátì, tí ó jẹ́ ará Gátì, ó wá láti ibùdó Fílístínì Ó ga ní ìwọ̀n mítà mẹ́ta Ó ní àsíborí idẹ ní orí rẹ̀, ó sì wọ ẹ̀wù tí a fi idẹ pẹlẹbẹ ṣe, ìwọ̀n ẹ̀wù náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣékélì idẹ, Òun sì wọ ìhámọ́ra idẹ sí ẹsẹ̀ rẹ̀ àti àpáta idẹ kan láàrin ẹ̀yìn rẹ̀ Ọ̀pá rẹ̀ rí bí apása ìhunṣọ, orí ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì wọn kilogírámù méje irin, ẹni tí ó ru asà ogun rẹ̀ lọ ṣáájú u rẹ̀ Gòláyátì dìde, ó sì kígbe sí ogun Ísírẹ́lì pé, Èéṣe tí ẹ̀yin fi jáde wá, tí ẹ ṣe tò fún ogun Ṣé èmi kì í ṣe Fílístínì ni, àbí ẹ̀yin kì í ṣe ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù Yan ọkùnrin kan kí o sì jẹ́ kí ó sọ̀kalẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi Tí òhun bá sì le jà tí ó sì pa mí, àwa yóò di ẹrú u yín, ṣùgbọ́n tí èmi bá lè ṣẹ́gun rẹ̀ tí mo sì pa á, ẹ̀yin yóò di ẹrú u wa, ẹ̀yin yóò sì máa sìn wá Nígbà náà Fílístínì náà wí pé, Èmi fi ìjà lọ ogun Ísírẹ́lì ní òní! Ẹ mú ọkùnrin kan wá kí ẹ sì jẹ́ kí a bá ara wa jà Nígbà tí Sáulù àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ Fílístínì, ìdààmú bá wọn Nísinsìn yìí Dáfídì jẹ́ ọmọ ará Éfúrátà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jésè, tí ó wá látí Bétílẹ́hẹ́mù ní Júdà, Jésè ní ọmọ mẹ́jọ, ní àsìkò Sáulù ó ti darúgbó ẹni ọdún púpọ̀ Àwọn ọmọ Jésè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ti dàgbà bá Ṣọ́ọ̀lù lọ sí ojú ogun Èyí àkọ́bí ni Élíábù Èyí èkejì ni Ábínádábù, èyí ẹ̀kẹta sì ní Ṣámínà Dáfídì ni ó kéré jù nínú wọn Àwọn àgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì tẹ̀lé Ṣọ́ọ̀lù, Ṣùgbọ́n Dáfídì padà lẹ́yìn Ṣọ́ọ̀lù, láti máa tọ́jú àgùntàn baba rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Fún ogójì ọjọ́, Fílístínì wá ṣíwájú ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ wọ́n sì fi ara wọn hàn Nísinsìn yìí Jésè wí fún ọmọ rẹ̀ Dáfídì pé, Mú ìwọ̀n éfà àti àgbàdo yíyan àti ìṣù àkàrà mẹ́wàá lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ kí o sì ṣéré lọ sí ibùdó o wọn Kí o sì mú wàrà mẹ́wàá yìí lọ́wọ́ fún adarí ogun ti wọn Wo bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe wà kí o sì padà wá fún mi ní àmìn ìdánilójú láti ọ̀dọ̀ wọn Wọ́n wà pẹ̀lú u Ṣọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ní àfonífojì Élà, wọ́n bá àwọn Fílístínì jà Ní àárọ̀ kùtùkùtù Dáfídì fi agbo ẹran rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùtọ́jú, ó di ẹrù, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n gẹ́gẹ́ bí Jésè ti sọ fún un Ó dé ibùdó bí àwọn ọmọ ogun ti ń lọ láti dúró ní ipò wọn ní ojú ogun, wọ́n hó ìhó ogun Ísírẹ́lì àti Fílístínì lọ sí ojú ìjà wọ́n da ojú ìjà kọ ara wọn Dáfídì sì kó ẹrù rẹ̀ ti àwọn olùtọ́jú ohun èlò, ó sì sá lọ sí ojú ogun ó sì kí àwọn ẹ̀gbọ́n ọn rẹ̀ Bí ó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀, Gòláyátì akíkanjú Fílístínì tí ó wá láti Gátì yọra sí iwájú ní ojú ogun, ó sì kígbe fún ìpèníjà, Dáfídì sì gbọ́ Nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì rí ọkùnrin náà, gbogbo wọn sì sá fún un ní ìbẹ̀rù-bojo Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wí pé, Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ríi bí ọkùnrin yìí ṣe ń jáde wá Ó jáde wá láti pe Ísírẹ́lì níjà Ọba yóò fún ọkùnrin tí ó bá pa á ní ọrọ̀ púpọ̀ Yóò tún fi ọmọ rẹ̀ obìnrin fún un ní ìyàwó, yóò sì sọ ilé e baba rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú sísan owó orí ní Ísírẹ́lì Dáfídì béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin tí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹ rẹ̀ pé, Kí ni a ó ò ṣe fún ọkùnrin náà tí ó bá pa Fílístínì yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Ísírẹ́lì Ta ni aláìkọlà Fílístínì tí ó jẹ́ wí pé yóò máa gan ogun Ọlọ́run alààyè Wọ́n tún sọ fún un ohun tí wọ́n ti ń sọ, wọ́n sì wí pé, Èyí ni ohun tí wọn yóò ṣe fún ọkùnrin tí ó bá pa á Nígbà tí Élíábù ẹ̀gbọ́n Dáfídì gbọ́ nígbà tí ó ń bá ọkùnrin yìí sọ̀rọ̀, ó bínú sí i, ó sì wí pé, Kí ni ó dé tí ìwọ fi sọ̀kalẹ̀ wá síbí Àti pé ta ni ìwọ fi àwọn àgùntàn kékeré tó kù ṣọ́ ní ihà Èmi mọ ìgbéraga rẹ, àti búburú ọkàn rẹ ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá nìkan láti wòran ogun Dáfídì wí pé, Kí ni mo ṣe nísinsìn yìí Ǹjẹ́ mo lè sọ̀rọ̀ bí Ó sì yípadà sí ẹlòmíràn, ó sì ń sọ̀rọ̀ kán náà, ọkùnrin náà sì dáhùn bí ti ẹni ìṣáájú Àwọn ènìyàn gbọ́ ohun tí Dáfídì sọ wọ́n sọ fún Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì ránṣẹ́ sí i Dáfídì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí Fílístínì yìí, ìránṣẹ́ rẹ yóò lọ láti bá a jà Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, Ìwọ kò tó láti jáde lọ pàdé ogun Fílístínì yìí àti láti bá a jà ọmọdé ni iwọ́, òun sì ti ń jagun láti ìgbà èwe rẹ̀ wá Ṣùgbọ́n Dáfídì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ti ń tọ́jú agbo àgùntàn baba rẹ̀ Nígbà tí kìnìún tàbí àmọ̀tẹ́kùn bá wá láti wá gbé àgùntàn láti inú igbó Mo sá tẹ̀lé e, mo lù ú, mo sì gba àgùntàn náà kúrò lẹ́nu rẹ̀ Nígbà tí ó kọjú sí mi, mo fi irun rẹ̀ gbá a mú, mo sì lù ú mo sì pa á Ìránṣẹ́ rẹ ti pa kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn, aláìkọlà Fílístínì yìí yóò jẹ́ ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pe ogun Ọlọ́run alààyè ní ìjà Olúwa tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìhàlẹ̀ kìnnìún àti ti ìhàlẹ̀ àmọ̀tẹ́kùn yóò gbà mí kúrò lọ́wọ́ Fílístínì yìí Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, Lọ kí Olúwa wà pẹ̀lú ù rẹ Ṣọ́ọ̀lù fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ wọ Dáfídì, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìhámọ́ra ogun, ó sì fi ìbòrí idẹ kan bò ó ní orí Dáfídì si di idà rẹ̀ mọ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn káàkiri nítorí wí pé kò mọ́ ọ lára Ó sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Èmi kò le wọ èyí lọ, kò mọ́ mi lára Ó sì bọ́ wọn kúrò Nígbà náà, ó sì mú ọ̀pá a rẹ̀ lọ́wọ́, ó ṣa òkúta dídán márùn ún létí odò, ó kó wọn sí àpò olùṣọ́ àgùntàn tí ó wà lọ́wọ́ ọ rẹ̀ pẹ̀lú kànnàkànnà Lákòókò yìí, Fílístínì pẹ̀lú ẹni tí ń gbé ìhámọ́ra ààbò wà níwájú rẹ̀, ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ Dáfídì Ó wo Dáfídì láti òkè délẹ̀, ó sì rí i wí pé ọmọ kékeré kùnrin ni, ó pọ́n ó sì lẹ́wà lójú, ó sì kẹ́gàn an rẹ̀ Ó sì wí fún Dáfídì pé, Ṣé ajá ni mí ni Tí o fi tọ̀ mí wá pẹ̀lú ọ̀pá Fílístínì sì gbé Dáfídì bú pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀ Ó wí pé, Wá níbí, èmi yóò fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ àti fún àwọn ẹranko tí ó wà nínú igbó! Dáfídì sì wí fún Fílístínì pé, Ìwọ dojú ìjà kọ mí pẹ̀lú idà, ọ̀kọ̀ àti ọfà, ṣùgbọ́n èmi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Olúwa àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tí ìwọ tí gàn Lónìí yìí ni Olúwa yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, èmi yóò sì pa ọ́, èmi yóò sì gé orí ì rẹ Lónìí èmi yóò fi òkú ogun Fílístínì fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ìgbó, gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà ní Ísírẹ́lì Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni Olúwa fi ń gbàlà ogun náà ti Olúwa ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ ọ wa Bí Fílístínì ṣe súnmọ́ iwájú láti pàdé e rẹ̀ Dáfídì yára sáré sí oun náà láti pàdé e rẹ̀ Ó ti ọwọ́ sí àpò rẹ̀ ó sì mú òkúta jáde wá ó sì fì í, ó sì jù ú sí ọ̀kọ́kán iwájú orí Fílístínì Òkúta náà sì wọ̀ ọ́ níwájú orí, ó sì ṣubú ó sì dojúbolẹ̀ ní orí ilẹ̀ Dáfídì yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Fílístínì pẹ̀lú kànnàkànnà àti òkúta, láìsí idà ní ọwọ́ rẹ̀, ó lu Fílístínì ó sì pa á Dáfídì sì sáré ó sì dúró lórí rẹ̀ Ó sì mú idà Fílístínì, ó sì fà á yọ nínú àkọ̀ ọ rẹ̀ Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa á tan, ó sì gé orí i rẹ̀ pẹ̀lú idà Nígbà tí àwọn ará Fílístínì rí i wí pé akọni wọn ti kú, wọ́n yípadà wọ́n sì sálọ Nígbà náà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti ti Júdà súnmọ́ iwájú pẹ̀lú ariwo, wọ́n sì lépa àwọn ará Fílístínì dé ẹnu ibodè Gátì àti títí dé ẹnu ibodè Ékírónì Àwọn tí ó kú wà káàkiri ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà Ṣáráímù àti títí dé ọ̀nà Gátì àti Ékírónì Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì padà láti máa lé àwọn ará Fílístínì, wọ́n sì ba ibùdó wọn jẹ́ Dáfídì gé orí Fílístínì ó sì gbé e wá sí Jérúsálẹ́mù, ó sì kó àwọn ohun ìjà Fílístínì sìnú àgọ́ tirẹ̀ Bí Ṣọ́ọ̀lù sì ti wo Dáfídì bí ó ṣe ń jáde lọ pàdé Fílístínì, ó wí fún Ábínérì, olórí àwọn ológun rẹ̀ pé, Ábínérì, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí Ábínérì dáhùn pe, Bí ọkàn rẹ̀ ti ń bẹ ní ààyè, ọba èmi kò mọ̀ Ọba sì wí pé, Wádìí ọmọ ẹni tí ọmọdékùnrin náà ń ṣe Gbàrà tí ó dé láti ibi tí ó ti lọ pa Fílístínì, Ábínérì sì mú u wá ṣíwájú u Ṣọ́ọ̀lù, orí Fílístínì sì wà ní ọwọ́ Dáfídì Ṣọ́ọ̀lù béèrè pé, Ọmọdékùnrin, ọmọ ta ni ọ́ Dáfídì dáhùn pé, Èmi ni ọmọ ìránṣẹ́ rẹ Jésè ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Ṣọ́ọ̀lù Ń Jowú Dáfídì Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá Ṣọ́ọ̀lù sọ, ọkàn Jónátanì di ọ̀kan pẹ̀lú ti Dáfídì, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀ Láti ọjọ́ náà Ṣọ́ọ̀lù pa Dáfídì mọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì jẹ́ kí ó padà sí ilé baba rẹ̀ mọ́ Jónátanì bá Dáfídì dá májẹ̀mú nítorí tí ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀ Jónátanì sì bọ́ aṣọ ìgúnwà, ó sì fi fun Dáfídì pẹ̀lú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ àti pẹ̀lú idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti àmùrè rẹ̀ Ohunkóhun tí Ṣọ́ọ̀lù bá rán an láti ṣe, Dáfídì máa ṣe ní àṣeyọrí, Ṣọ́ọ̀lù náà sì fun un ní ipò tí ó ga jù láàrin àwọn ológun Eléyìí sì tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn, àti pẹ̀lú ó sì tẹ́ àwọn ìjòyè Ṣọ́ọ̀lù lọ́rùn pẹ̀lú Nígbà tí àwọn ènìyàn padà sí ilé lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti pa Fílístínì, gbogbo àwọn obìnrin tú jáde láti inú ìlú Ísírẹ́lì wá láti pàdé ọba Ṣọ́ọ̀lù pẹ̀lú orin àti ijó, pẹ̀lú orin ayọ̀ àti tamborínì àti ohun èlò orin Bí wọ́n ṣe ń jó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọrin pé Ṣọ́ọ̀lù pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀ Dáfídì sì pa ẹgbẹgbàárún ní tirẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù sì bínú gidigidi, ọ̀rọ̀ náà sì korò létí rẹ̀ pé, Wọ́n ti gbé ògo fún Dáfídì pẹ̀lú ẹgbẹgbàárún ó sì wí pé, Ṣùgbọ́n èmi pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan Kí ni ó kù kí ó gbà bí kò ṣe ìjọba Lati ìgbà náà lọ ni Ṣọ́ọ̀lù ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ojú ìlára wo Dáfídì Ní ọjọ́ kejì ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pẹ̀lú agbára sórí Ṣọ́ọ̀lù, ó sì sọ àṣọtẹ́lẹ̀ ní ilé rẹ̀ nígbà tí Dáfídì sì ń fọn ohun èlò orin olókùn, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe láti ẹ̀yìn wá, Ṣọ́ọ̀lù sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀ Ó sì gbé e sókè, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, Èmi yóò gún Dáfídì pọ̀ mọ́ ògiri Ṣùgbọ́n, Dáfídì yẹ̀ fún un lẹ́ẹ̀méjì Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ̀rù Dáfídì nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Dáfídì, ṣùgbọ́n ó ti fi Ṣọ́ọ̀lù sílẹ̀ Ó sì lé Dáfídì jáde ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fi jẹ olórí ogun ẹgbẹ̀rún kan, Dáfídì ń kó wọn lọ, ó ń kó wọn bọ̀ nínú ìgbòkègbodò ogun Nínú ohun tí ó bá ṣe, ó ń ní àṣeyọrí ńlá, nítorí tí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀ Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù rí bi àṣeyọrí rẹ̀ ti tó, ó sì bẹ̀rù rẹ̀ Ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà ni wọ́n fẹ́ràn Dáfídì, nítorí ó darí wọn ní ìgbòkègbodò ogun wọn Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Mérábù Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa Nítorí tí Ṣọ́ọ̀lù wí fún ara rẹ̀ pé, Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè síi Jẹ́ kí àwọn Fílístínì ṣe èyí Ṣùgbọ́n Dáfídì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Ta ni mí, kí sì ni ìdílé mi tàbí ìdílé baba mi ní Ísírẹ́lì, tí èmi yóò di àna ọba Nígbà tí àkókò tó fún Mérábù, ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù, láti fi fún Dáfídì, ni a sì fi fún Ádíríélì ara Méhólátì ní aya Nísinsìn yìí ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù Míkálì sì fẹ́ràn Dáfídì, nígbà tí wọ́n sọ fún Ṣọ́ọ̀lù nípa rẹ̀, ó sì dùn mọ́ ọn Ó sọ nínú ara rẹ̀ pé, Èmi yóò fi fún un kí òun ba à le jẹ́ tàkúté fún un, kí ọwọ́ àwọn ará Fílístínì lè wà lára rẹ̀ Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, Nísinsìn yìí ìwọ ní àǹfààní eléyìí láti jẹ́ àna àn mi Ṣọ́ọ̀lù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ sọ fún Dáfídì ní ìkọ̀kọ̀, kí ẹ sì wí pé, Wò ó, inú ọba dùn sí ọ, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni ó fẹ́ràn rẹ, nísinsìn yìí jẹ́ àna ọba   Wọ́n tún ọ̀rọ̀ náà sọ fún Dáfídì Ṣùgbọ́n Dáfídì wí pé, Ṣé ẹ rò pé ohun kékeré ni láti jẹ́ àna ọba Mo jẹ́ tálákà ènìyàn àti onímọ̀ kékeré Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sọ fún un ohun tí Dáfídì sọ, Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, Sọ fún Dáfídì pé, Ọba kò fẹ́ owó orí láti ọ̀dọ̀ àna rẹ̀ ju awọ iwájú orí ọgọ́rùn ún Fílístínì lọ láti fi gba ẹ̀san lórí àwọn ọ̀ta rẹ̀   Èrò Ṣọ́ọ̀lù ni wí pé kí Dáfídì ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Fílístínì Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún Dáfídì, inú rẹ̀ dùn láti di àna ọba kí àkókò tí ó dá tó kọjá, Dáfídì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ wọ́n sì pa igba lára àwọn Fílístínì Ó kó awọ iwájú orí wọn wá, ó sì pé iye tí ọba fẹ́ kí ó baà lè jẹ́ àna ọba Ṣọ́ọ̀lù sì fi ọmọ obìnrin Míkálì fún un ní aya Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì wá mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú Dáfídì tí ọmọbìnrin rẹ̀ Míkálì sì fẹ́ràn Dáfídì, Ṣọ́ọ̀lù sì tún wá bẹ̀rù rẹ̀ sí, ó sì jẹ́ ọ̀ta rẹ̀ fún gbogbo ọjọ́ rẹ̀ tó kù Àwọn olórí ogun Fílístínì tún tẹ̀ṣíwájú láti lọ sí ogun, ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ, Dáfídì ṣe àṣeyọrí ju gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù lọ, orúkọ rẹ̀ sì gbilẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù Gbìyànjú Láti Pa Dáfídì Ṣọ́ọ̀lù sọ fún Jónátanì ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dáfídì Ṣùgbọ́n Jónátanì fẹ́ràn Dáfídì púpọ̀ Ó sì kìlọ̀ fún un pé, Baba mi Ṣọ́ọ̀lù wá ọ̀nà láti pa ọ́, kíyèsí ara rẹ di òwúrọ̀ ọ̀la lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀, kí o sì sá pamọ́ sí ibẹ̀ Èmi yóò jáde lọ láti dúró ní ọ̀dọ̀ baba mi ní orí pápá níbi tí ó wà Èmi yóò sọ̀rọ̀ fún un nípa à rẹ, èmi yóò sì sọ ohun tí òun bá wí fún ọ Jónátanì sọ̀rọ̀ rere nípa Dáfídì fún Ṣọ́ọ̀lù baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀ Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu nígbà tí ó pa Fílístínì Olúwa ṣẹ́ ogun ńlá fún gbogbo Ísírẹ́lì, ìwọ rí i inú rẹ dùn Èéṣe nígbà náà tí ìwọ yóò fi ṣe ohun búburú sí ọkùnrin aláìṣẹ̀ láìnídìí Ṣọ́ọ̀lù fetísí Jónátanì, ó sì búra báyìí, Níwọ̀n ìgbà tí Olúwa bá ti ń bẹ láàyè, a kì yóò pa Dáfídì Nítorí náà Jónátanì pe Dáfídì, ó sì sọ gbogbo àjọsọ wọn fún un Ó sì mú un wá fún Ṣọ́ọ̀lù, Dáfídì sì wà lọ́dọ̀ Ṣọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ Lẹ́ẹ̀kàn an sí i ogun tún wá, Dáfídì sì jáde lọ, ó sì bá àwọn ara Fílístínì jà Ó sì pa wọn pẹ̀lú agbára, wọ́n sì sálọ níwájú u rẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí orí Ṣọ́ọ̀lù bí ó ti jókòó ní ilé e rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ rẹ̀ Bí Dáfídì sì ti fọn ohun èlò orin olókùn, Ṣọ́ọ̀lù sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dáfídì yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ṣọ́ọ̀lù ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dáfídì sì fi ara pamọ́ dáradára Ṣọ́ọ̀lù rán ènìyàn sí ilé Dáfídì láti sọ́ ọ kí wọ́n sì pa á ní òwúrọ̀ Ṣùgbọ́n Míkálì, ìyàwó Dáfídì kìlọ̀ fún un pé, Tí o kò bá sá fún ẹ̀mí ì rẹ ní alẹ́ yìí, ní ọ̀la ni a ó ò pa ọ́ Nígbà náà Míkálì sì gbé Dáfídì sọ̀kalẹ̀ ó sì fi aṣọ bò ó Míkálì gbé ère ó sì tẹ́ e lórí ibùsùn, ó sì fi irun ewúrẹ́ sí ibi orí rẹ̀ Nígbà ti Ṣọ́ọ̀lù rán ènìyàn láti lọ fi agbára mú Dáfídì, Míkálì wí pé, Ó rẹ̀ ẹ́ Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù rán ọkùnrin náà padà láti lọ wo Dáfídì ó sì sọ fún wọn pé, Mú wa fún mi láti orí ibùsùn rẹ̀ kí èmi kí ó le pa á Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ère ni ó bá lórí ibùsùn àti irun ewúrẹ́ ní orí ère náà Ṣọ́ọ̀lù wí fún Míkálì pé, Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí báyìí tí o sì jẹ́ kí ọ̀ta mi sálọ tí ó sì bọ́ Míkálì sọ fún un pé, Ó wí fún mi, jẹ́ kí èmi ó lọ Èéṣe tí èmi yóò fi pa ọ́ Nígbà tí Dáfídì ti sá lọ tí ó sì ti bọ́, ó sì lọ sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì ní Rámà ó sì sọ gbogbo ohun tí Ṣọ́ọ̀lù ti ṣe fún un Òun àti Sámúẹ́lì lọ sí Náíótì láti dúró níbẹ̀ Ọ̀rọ̀ sì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá pé, Dáfídì wà ní Náíótì ní Rámà, ó sì rán àwọn ènìyàn láti fi agbára mú u wá ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì tí ń ṣọtẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Sámúẹ́lì dúró níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí, ẹ̀mí Ọlọ́run sì wá sórí àwọn arákùnrin Ṣọ́ọ̀lù àwọn náà sì ń ṣọtẹ́lẹ̀ Wọ́n sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù nípa rẹ̀, ó sì rán ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn lọ àwọn náà sì ń ṣọtẹ́lẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù tún rán oníṣẹ́ lọ ní ìgbà kẹta, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣọtẹ́lẹ̀ Nígbẹ̀yìn, òun fúnra rẹ̀ sì lọ sí Rámà ó sì dé ibi àmù ńlá kan ní Ṣékù Ó sì béèrè, Níbo ni Sámúẹ́lì àti Dáfídì wà Wọ́n wí pé, Wọ́n wà ní ìrékọjá ní Náíótì ní Rámà Ṣọ́ọ̀lù sì lọ sí Náíótì ni Rámà Ṣùgbọ́n, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e lórí ó sì ń lọ lọ́nà, ó sì ń ṣọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Náíótì Ó sì bọ́ aṣọ rẹ̀, òun pẹ̀lú sì ń ṣọtẹ́lẹ̀ níwájú Sámúẹ́lì Ó sì dùbúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà àti ní òru Ìdí nìyìí tí àwọn ènìyàn fi wí pé, Ṣé Ṣọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn wòlíì ni Hánà Kọrin Ìyìn Sí Hánà sì gbàdúrà pé Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa Ìwọ agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀ta mi, nítorí ti èmi yọ̀ ni igbala rẹ̀ Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa kò sí ẹlòmíràn bí kò se ìwọ kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa Má ṣe halẹ̀ má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa , láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà Ọrun àwọn alágbára ti ṣẹ́, àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè Àwọn tí ó yọ̀ fún òunjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe, àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní tóbẹ́ẹ̀ ti àgàn fi bí méje Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára Olúwa pa ó sì sọ di ààyè ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà-òkú, ó sì gbé dìde Olúwa sọ di talákà ó sì sọ di ọlọ́rọ̀ ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkítì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ogo Nítorí pé ọ̀wọ̀n ayé ti Olúwa ni, ó sì ti gbé ayé ka orí wọn Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́, àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí A ó fọ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú láti ọrun wá ni yóò sánààrá sí wọn Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀, yóò si gbé ìwo ẹni-àmì-òróró rẹ̀ sókè Elikánà sì lọ sí Rámà sí ilé rẹ̀, Ọmọ náà sì ń ṣe ìráńṣẹ́ fún Olúwa níwájú Élì àlùfáà Àwọn ọmọ Élì sì jẹ́ ọmọ Bélíálì wọn kò mọ Olúwa Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìráńṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀ Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí Kẹ́tìlì tàbí òdù, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣílò Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìráńṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfàá nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò se tútù Bí ọkùnrin náà bá sì wí fún un pé, Jẹ́ kí wọn ó sun ọ̀rá náà nísinsin yìí, kí o sì mú iyekíye tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́ nígbà náà ni yóò dá a lóhùn pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi í fún mi nísinsin yìí, bí kó ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó fi agbára gbà á Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùrin náà sì tóbi gidigidi níwájú Olúwa nítorí tí ènìyàn kórìíra ẹbọ Olúwa Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì ń ṣe ìráńṣẹ́ níwájú Olúwa , ọmọdé, ti a wọ̀ ní éfódì ọ̀gbọ̀ Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ ìlekè péńpé fún un, a sì máa mu wá fún un lọdọọdún, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ gòkè wá láti ṣe ìrúbọ ọdún Élì súre fún Elikánà àti aya rẹ̀ pé, Kí Olúwa fún ọ ní irú-ọmọ láti ara obìnrin yìí wá, nítorí ẹ̀bùn tí ó béèrè tí ó sì tún fún Olúwa Wọ́n sì lọ sí ilé wọn Olúwa si bojú wo Hánà, ó sì lóyún, ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì Sámúẹ́lì ọmọ náà sì ń dàgbà níwájú Olúwa Élì sì di arúgbó gidigidi, ó sì gbọ́ gbogbo èyí ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sí gbogbo Ísírẹ́lì àti bi wọ́n ti máa ń bá àwọn obìnrin sùn, tí wọ́n máa ń péjọ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ Ó sì wí fún wọn pé, kí ni ó ti ri Èétirí tí èmi fi ń gbọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí yín Nítorí tí èmi ń gbọ́ iṣẹ́ búburú yín láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí kì ṣe ìròyìn rere èmi gbọ́ ẹyin mú ènìyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀ Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì, onídàájọ́ yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí Olúwa , tani yóò bẹ̀bẹ̀ fún un Wọn kò sì fi etí sí ohùn baba wọn, nítorí tí Olúwa ń fẹ́ pa wọ́n Ọmọ náà Sámúẹ́lì ń dàgbà, ó sì rí ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa , àti ènìyàn pẹ̀lú Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Élì wá, ó sì wí fún un pé, Báyìí ni Olúwa wí, Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ̀, nígbà tí wọ́n ń bẹ nínú ilé Fáráò Èmi Éjíbítì sì yàn án kúrò láàrin gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti jẹ́ àlùfáà mi, láti rúbọ lórí pẹpẹ mi, lati fi tùràrí jóná, láti wọ éfódì níwájú mi, èmi sì fi gbogbo ẹbọ tí ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi iná sun fún ìdílé baba rẹ̀ Èé ha ṣe tí ẹ̀yin fi tàpá sí ẹbọ àti ọrẹ mi, tí mo páṣẹ ní ibùjókòó mi ìwọ sì bu ọlá fún àwọn ọmọ rẹ jú mí lọ, tí ẹ sì fi gbogbo àṣàyàn ẹbọ Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn mi mú ara yín sanra Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa wí pé, Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí Kíyèsí i, àwọn ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi ó gé agbára rẹ kúrò, àti agbára baba rẹ, tí kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ Nínú wàhálà ni ìwọ yóò fí ìlará wó gbogbo ọlá ti Ọlọ́run yóò fi fún Ísírẹ́lì kì yóò sì sí arúgbó kan nínú ilé baba rẹ láéláé Ọkùnrin tí ó jẹ́ tìrẹ, tí èmi kì yóò gé kúrò ni ibi pẹpẹ mi ni a ó dá sí láti sunkún yọ lójú àti láti banújẹ́ Ṣùgbọ́n gbogbo irú-ọmọ ilé rẹ̀ ni a ó fi idà pa ní ààbọ̀ ọjọ́ wọn  Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ọkùnrin rẹ̀ méjèèjì, Hófínì àti Fínéhásì, yóò jẹ́ àmì fún ọ, àwọn méjèèjì yóò kú ní ọjọ́ kan náà Èmi yóò dìde fún ara mi láti gbé àlùfáà olódodo dìde fún ara mi ẹni tí yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wà ní ọkàn mi àti inú mi Èmi yóò fi ẹṣẹ̀ ilé rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in òun yóò sì ṣe òjíṣẹ́ níwájú ẹni òróró mi ní ọjọ́ gbogbo Nígbà náà olúkúlùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá kù ní ìdílé yín, yóò jáde wá yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀ nítorí ẹyọ fàdákà àti nítorí èépá àkàrà àti ẹ̀bẹ̀ pé, Jọ̀wọ́ yàn mí sí ọ̀kan nínú iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí èmi kí ó le máa rí oúnjẹ jẹ    Dáfídì àti Jónátanì Nígbà náà ni Dáfídì sá kúrò ní Naíótì ti Rámà ó sì lọ sọ́dọ̀ Jónátanì ó sì béèrè pé, Kí ni mo ṣe Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi Báwo ni mo ṣe ṣẹ baba rẹ, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí mi Jónátanì dáhùn pé, Kí a má rí i! Ìwọ kò ní kú! Wò ó baba mi kì í ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí tí ó kéré, láì fi lọ̀ mí Èéṣe tí yóò fi fi èyí pamọ́ fún mi Kò rí bẹ́ẹ̀ Ṣùgbọ́n Dáfídì tún búra, ó sì wí pé, Baba rẹ mọ̀ dáradára pé mo rí ojú rere ní ojú ù rẹ, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, Jónátanì kò gbọdọ̀ mọ èyí yóò sì bà á nínú jẹ́ Ṣíbẹ̀ nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láàyè àti gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà láàyè, ìgbésẹ̀ kan ni ó wà láàrin èmi àti ikú Jónátanì wí fún Dáfídì pé, Ohunkóhun tí ìwọ bá ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe, èmi yóò ṣe é fún ọ Dáfídì wí pé, Wò ó, ọ̀la ni oṣù tuntun, mo sì gbọdọ́ bá ọba jẹun, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó lọ láti fi ara pamọ́ lórí pápá títí di àṣálẹ́ ọjọ́ kẹta Tí baba rẹ bá fẹ́ mi kù, sọ fún un pé, Dáfídì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ààyè láti sáré lọ sí ìlú rẹ̀ nítorí wọ́n ń ṣe ẹbọ ọdọọdún ní ibẹ̀ fún gbogbo ìdílé rẹ̀ Tí o bá wí pé, Ó dára náà, nígbà náà, ìránṣẹ́ rẹ wà láìléwu Ṣùgbọ́n tí ó bá bínú gidigidi, ìwọ yóò mọ̀ dájú pé ó pinnu láti ṣe ìpalára mi Ṣùgbọ́n ní tirẹ ìwọ, fi ojú rere wo ìránṣẹ́ rẹ nítorí tí ìwọ ti báa dá májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ níwájú Olúwa Tí mo bá jẹ̀bi, pa mí fún ara rẹ! Èéṣe tí ìwọ yóò fi fi mí lé baba rẹ lọ́wọ́ Jónátanì wí pé, Kí a má ríi! Ti mo bá ti gbọ́ tí baba mi ti pinnu láti pa ọ́ lára, ṣé èmi kò ní sọ fún ọ Dáfídì sì béèrè pé, Ta ni yóò sọ fún mi tí baba rẹ̀ bá dá ọ lóhùn ní ohùn líle Jónátanì wí pé, Wá, jẹ́ kí a jáde lọ sórí pápá Nígbà náà wọ́n sì jáde lọ Nígbà náà ni Jónátanì sọ fún Dáfídì Pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì, èmi yóò rí i dájú pé mo gbọ́ ti ẹnu baba mi ní ìwòyí ọ̀la tàbí ní ọ̀túnla tí ó bá sì ní ojú rere ní inú dídùn sí ọ, tí èmi kò bá ránṣẹ́ sí ọ, kí èmi sì jẹ́ kí o mọ̀ Ṣùgbọ́n tí baba mi kò bá ní ìfẹ́ sí pa ọ́ lára, kí Olúwa kí ó dí ìyà jẹ mí, tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí n kò bá jẹ́ kí o mọ̀, kí n sì jẹ́ kí o lọ ní àlàáfíà Kí Olúwa kí ó pẹ̀lú ù rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹ̀lú baba mi Ṣùgbọ́n fi inú rere àìkùnà hàn mí Níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè kí wọ́n má ba à pa mí, Má ṣe ké àánú rẹ kúrò lórí ìdílé mi títí láé Bí Olúwa tilẹ̀ ké gbogbo ọ̀ta Dáfídì kúrò lórí ilẹ̀ Nígbà náà ni Jónátanìf bá ilé Dáfídì dá májẹ̀mú wí pé, Olúwa yóò pe àwọn àti Dáfídì láti sírò Jónátanì mú kí Dáfídì tún ìbúra ṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní síi, nítorí tí ó fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ràn ara rẹ̀ Nígbà náà ni Jónátanì wí fún Dáfídì pé, Lọ́la ní ibi àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, a ó ò fẹ́ ọ kù, nítorí àyè rẹ yóò ṣófo Ní ọ̀túnla lọ́wọ́ alẹ́ lọ sí bi tí o sá pamọ́ sí nígbà tí ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀, kí o sì dúró níbi òkúta Ésélù Èmi yóò ta ọfà mẹ́ta sí ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀, gẹ́gẹ́ bí i pé mo ta á sí àmì ibìkan Èmi yóò rán ọmọdékùnrin kan èmi yóò wí fún un wí pé, Lọ, kí o lọ wá ọfà náà Tí mo bá sọ fún-un wí pé, wò ó, ọfà wọ̀nyí wà ní ibi báyìí ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ rẹ kó wọn wá síbí kí o sì wá, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wà ní ààyè, o wà ní àlàáfíà kò sí ewú Ṣùgbọ́n tí mo bá sọ fún ọmọdékùnrin náà pé, wò ó, àwọn ọfà náà kọjá níwájú rẹ nígbà náà, o gbọdọ̀ lọ, nítorí Olúwa ti rán ọ jáde lọ Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi àti ìwọ jọ sọ, rántí Olúwa jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrin ìwọ àti èmi títí láéláé Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sá pamọ́ sínú pápá Nígbà tí àṣè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun sì dé, ọba sì jókòó láti jẹun Ó sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ipò o rẹ̀ ní ibi tí ó máa ń ijòkòó lórí ìjòkó tí ó wà lẹ́gbẹ̀ ẹ́ ògiri, ní òdìkejì Jónátanì, Ábínérì sì jókòó ti Ṣọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n àyè Dáfídì sì ṣófo Ṣọ́ọ̀lù kò sọ nǹkan kan ní ọjọ́ náà, nítorí ó rò pé, Nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì láti jẹ́ kí ó di aláìmọ́ lótìítọ́ ó jẹ́ aláìmọ́ Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, ní ọjọ́ kejì oṣù, ààyè Dáfídì sì tún ṣófo Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún ọmọ rẹ̀ Jónátanì pé, Kí ni ó dé tí ọmọ Jésè kò fi wá síbi oúnjẹ, lánàá àti lónìí Jónátanì sì dáhùn pé, Dáfídì bẹ̀ mí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fún ààyè láti lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Ó wí pé, Jẹ́ kí n lọ, nítorí pé ìdílé wa ń ṣe ìrúbọ ní ìlú, àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi sì ti pàṣẹ fún mi láti wà níbẹ̀ tí èmi bá rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí n lọ láti lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi Ìdí nì yí tí kò fi wá sí orí tábìlì oúnjẹ ọba Ìbínú Ṣọ́ọ̀lù sì ru sí Jónátanì ó sì wí fún un pé, Ìwọ ọmọ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ búburú yìí, ṣé èmi kò ti mọ̀ pé, ìwọ ti yan ọmọ Jésè fún ìtìjú ti ara rẹ àti fún ìtìjú mọ̀mọ́ rẹ tí ó bí ọ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jésè bá wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé, a kì yóò fi ẹṣẹ̀ ìwọ tàbí ti ìjọba rẹ múlẹ̀ Nísinsìn yìí ránṣẹ́ kí o sì lọ mú un wá fún mi, nítorí ó gbọ́dọ̀ kú! Jónátanì béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, Èéṣe tí àwa yóò fi pa á Kí ni ó ṣe Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Jónátánì láti gún un pa Nígbà náà ni Jónátanì mọ̀ pé baba rẹ̀ mọ̀ ọ́n mọ̀ fẹ́ pa Dáfídì ni Bẹ́ẹ̀ ni Jónátanì sì fi ìbínú dìde kúrò ni ibi oúnjẹ, kò sì jẹun ni ọjọ́ kejì oṣù náà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi fún Dáfídì, nítorí pé baba rẹ̀ dójú tì í Ó sì ṣe, ní òwúrọ̀ ni Jónátanì jáde lọ sí oko ní àkókò tí òun àti Dáfídì ti fí àdéhùn sí, ọmọdekùnrin kan sì wá pẹ̀lú rẹ̀ Ó si wí fún ọmọdékùnrin rẹ̀ pé, Sáré, kí o si wá àwọn ọfà tí èmi ó ta Bí ọmọdé náà sì ti ń sáré, òun sì tafà rékọjá rẹ̀ Nígbà tí ọmọdékùnrin náà sì dé ibi ọfà tí Jónátanì ta, Jónátanì sì kọ sí ọmọdékùnrin náà ó sì wí pé, Ọfà náà kò ha wà níwájú rẹ bi Jónátanì sì kọ sí ọmọdékùnrin náà pé, Sáré! Yára! Má ṣe dúró! Ọmọdékùnrin Jónátanì sì ṣa àwọn ọfà náà, ó sì tọ olúwa rẹ̀ wá Jónátanì sì fí apó àti ọrun rẹ̀ fún ọmọdékùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, Lọ, kí o sì mú wọn lọ sí ìlú Para Bí ọmọdékùnrin náà ti lọ tán, Dáfídì sì dìde láti ibi òkúta náà, ó sì wólẹ̀, ó sì tẹríba ní ìdojúbolẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta fún Jónátanì wọ́n sì fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọ́n sì jùmọ̀ sunkún, èkín-ín-ní pẹ̀lú ikejì rẹ̀, ṣùgbọ́n áfídì sunkún púpọ̀ jù Jónátanì sì wí fún Dáfídì pé, Má a lọ ní àlàáfíà, bí o ti jẹ́ pé àwa méjèèjì tí júmọ búra ni orukọ Olúwa pé, Ki Olúwa ó wà láàrin èmi àti ìwọ, láàrin irú-ọmọ mi àti láàrin irú-ọmọ rẹ̀ láéláé   Òun sì dìde, ó sì lọ kúrò Jónátanì sì lọ sí ìlú Áhímélékì Àlùfáà Fún Dáfídì Ni Àkàrà Mímọ́ Jẹ Dáfídì sì wá sí Nóbù sọ́dọ̀ Áhímélékì àlùfáà, Áhímélékì sì bẹ̀rù láti pàdé Dáfídì, ó sì wí fún un pé, Èé ha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ Dáfídì sì wí fún Áhímélékì àlùfáà pé, Ọbá pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí Ǹjẹ́ kín ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ Fún mi ni ìṣù àkàrà márùn ún tabi ohunkohun tí o bá rí Àlùfáà náà sí dá Dáfídì lóhùn ó sì wí pé, Kò sí àkàrà mìíràn lọ́wọ́ mi bí kò ṣe àkàrà mímọ́ Kìkì pé bi àwọn ọmọkùnrin bá ti pá ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin! Dáfídì sì dá àlùfáà náà lóhùn, ó sì wí fún un pé, Nítòótọ́ ni a tí ń pa ara wá mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin nígbàkùúgbà ti mo bá jáde ìrìn-àjò, gbogbo nǹkan àwọn ọmọkùnrin náà ni ó mọ́, pàápàá nígbà ìrìn-àjò kékèké kò há ní mọ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ lónìí bí Bẹ́ẹ̀ ni àlùfáà náà sì fí àkàrà mímọ́ fún un nítorí tí kò sí àkàrà mìíràn nibẹ̀ bí kò ṣe àkàrà ìfihàn tí a ti kó kúrò níwájú Olúwa , láti fi àkàrà gbígbóná síbẹ̀ ní ọjọ́ tí a kó o kúrò Ọkùnrin kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ níbẹ̀ lọ́jọ́ náà, tí a tí dá dúró síwájú Olúwa orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Dóégì, ará Édómù olórí nínú àwọn darandaran Ṣọ́ọ̀lù Dáfídì sì tún wí fún Áhímélékì pé, Kò sí ọ̀kọ̀ tàbí idà lọ́wọ́ rẹ níhìn Nítorí tí èmi kò mú idà mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mú nǹkan ìjà mi lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ ọba náà jẹ́ iṣẹ́ ìkánjú Àlùfáà náà sì wí pé, Idàn Gòláyátì ará Fílístínì tí ó pa ní àfonífojì Élà ní ń bẹ, wò ó, a fi aṣọ kan wé e lẹ́yìn Éródù bí ìwọ yóò bá mú èyí, mú un kò sì sí òmíràn níhìn mọ́ bí kò ṣe ọ̀kan náà Dáfídì sì wí pé, Kò sí èyí tí ó dàbí rẹ̀ fún mi Dáfídì sì dìde, o sì sá ni ọjọ́ náà níwájú Ṣọ́ọ̀lù, ó sì lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì, ọba Gátì Àwọn ìránṣẹ́ Ákíṣì sì wí fún un pé, Èyí há kọ́ ní Dáfídì ọba ilẹ̀ náà Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé,  Ṣọ́ọ̀lù pá ẹgbẹ̀rún tírẹ Dáfídì sì pa ẹgbàarún tirẹ̀ Dáfídì sì pa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí í mọ́ ni ọkàn rẹ̀, ó sì bẹ̀rù Ákíṣì ọba Gátì gidigidi Òun sì pa ìṣe rẹ̀ dà níwájú wọn, ó sì sọ ara rẹ̀ di aṣiwèrè ní ọwọ́ wọn, ó sì ń fi ọwọ́ rẹ̀ ha ilẹ̀kùn ojú ọ̀nà, ó sì ń wá itọ́ sí irungbọ̀n rẹ̀ Nígbà náà ni Ákíṣì wí fún àwọn ìrańṣẹ́ rẹ̀ pé, Wó o, nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe mú un tọ̀ mí wá Mo há ni un fi aṣiwèrè ṣe Tí ẹ̀yin fi mú èyí tọ̀ mí wá lati hú ìwà aṣiwèrè níwájú mi Eléyìí yóò há wọ inú ilé mi Dáfídì Sálọ Sí Ihò Ádúlámù Dáfídì sì kúrò níbẹ̀, ó sì sá sí ihò Ádúlámù nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìdílé baba rẹ̀ sì gbọ́, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá níbẹ̀ Olúkúlùkù ẹni tí ó tí wà nínú ipọ́njú, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ti jẹ gbésè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú ìbànújẹ́, sì kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun sì jẹ́ olórí wọn àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì tó iwọ̀n irinwó ọmọkùnrin Dáfídì sì ti ibẹ̀ náà lọ sí Mísípa tí Móábù ó sì wí fún ọba Móábù pé, Jẹ́ kí baba àti ìyá mi, èmi bẹ̀ ọ́ wá bá ọ gbé, títí èmi yóò fi mọ ohun ti Ọlọ́run yóò ṣe fún mi Ó sì mú wọn wá ṣíwájú ọba Móábù wọ́n sì bá á gbé ní gbogbo ọjọ́ tí Dáfídì fí wà nínú ihò náà Gádì wòlíì sí wí fún Dáfídì pé, Ma ṣe gbé inú ihò náà, yẹra, kí o sí lọ sí ilẹ̀ Júdà Nígbà náà ni Dáfídì sì yẹra, ó sì lọ sínú igbó Hárétì Ṣọ́ọ̀lù si gbọ́ pé a rí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ ní Gíbéà lábẹ́ igi kan ní Rámà ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó dúró tì í, pé, Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ ẹ̀yin ara Bẹ́ńjámínì, ọmọ Jésè yóò há fún olúkùlùkù yín ni oko ọgbà àjàrà bí Kí ó sì sọ gbogbo yin dì olórí ẹgbẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún bí Tí gbogbo yín di ìmọ̀lù sí mi, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó sọ létí mi pé, ọmọ mi ti bá ọmọ Jésè mulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kó sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó ṣàánú mi, tí ó sì sọ ọ́ létí mi pé, ọmọ mi mú kí ìránṣẹ́ mi dìde sí mi láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí Dóégì ara Édómù tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù, sì dáhùn wí pé, Èmi rí ọmọ Jésè, ó wá sí Nóbù, sọ́dọ̀ Áhímélékì ọmọ Áhítúbì Òun sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa fún un, ó sì fún un ní oúnjẹ́, kò sí fún un ni idà Gòláyátì ara Fílístínì Ọba sì ránṣẹ́ pe Áhímélékì àlùfáà, ọmọ Áhítúbì àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ni Nóbù gbogbo wọn ni ó sì wá sọ́dọ̀ ọba Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, Ǹjẹ́ gbọ́, ìwọ ọmọ Áhítúbì Òun sì wí pé, Èmi nìyìí Olúwa mi Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún un pé, Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi dìmọ̀lù sí mi, ìwọ àti ọmọ Jésè, tí ìwọ fi fún un ní àkàrà, àti idà, àti ti ìwọ fi béèré fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́run kí òun lè dìde sí mi, láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí Áhímélékì sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, Ta ni Olúwa rẹ̀ tí ó jẹ́ olóótọ́ nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ bí Dáfídì, ẹni tí ó jẹ́ àna ọba, ẹni tí ó ń gbọ́ tìrẹ, tí ó sì ni ọlá ni ilé rẹ Òní l'èmi ó ṣẹṣẹ̀ máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un bí Kí èyí jìnnà sí mi kí ọba má ṣe ka nǹkan kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, tàbí sí gbogbo ìdílé baba mi nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò mọ̀kan nínú gbogbo nǹkan yìí, díẹ̀ tabi púpọ̀ Ọba sì wí pé, Áhímélékì, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà Olúwa nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú Dáfídì, àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi, Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà Olúwa láti pa wọ́n Ọba sì wí fún Dóégì pé, Ìwọ yípadà, kí o sì pá àwọn àlùfáà! Dóégì ará Édómù sì yípadà, ó sì kọlu àwọn àlùfáà, ó sì pa wọ́n ní ọjọ́ náà, àrùnlélọ́gọ́rin ènìyàn ti ń wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ Éfọ́dú Ó sì fi ojú idà pa ara Nóbù, ìlú àwọn àlùfáà náà àti ọkùnrin àti obìnrin, ọmọ wẹ́wẹ́, àti àwọn tí ó wà lẹ́nu ọmú, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti àgùntàn Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Áhímélékì ọmọ Áhítúbì tí a ń pè ní Ábíátarì sì bọ́ ó sì sá àsálà tọ Dáfídì lọ Ábíátarì sì fi han Dáfídì pé Ṣọ́ọ̀lù pá àwọn àlùfáà Olúwa tán Dáfídì sì wí fún Ábíátarì pé, Èmi ti mọ̀ ní ọjọ́ náà, nígbà tí Dóégì ará Édómù ti wà níbẹ̀ pé, nítòótọ́ yóò sọ fún Ṣọ́ọ̀lù nítorí mi ni a ṣe pá gbogbo ìdílé baba rẹ Ìwọ jókòó níhin lọ́dọ̀ mi, má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé ẹni ti ń wá ẹ̀mi mi, ó ń wá ẹ̀mí rẹ Ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ mi ni ìwọ ó wà ní àìléwu Dáfídì Gbà Kéílà Lọ́wọ́ Àwọn Fílístínì Wọ́n sì wí fún Dáfídì pé, Ṣá wò ó, àwọn ará Fílístínì ń bá ará Kéílà jagun, wọ́n sì ja àwọn ilẹ̀ ìpakà lólè Dáfídì sì béèré lọ́dọ̀ Olúwa pé, Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Fílístínì wọ̀nyí bí Olúwa sì wí fún Dáfídì pé, Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Fílístínì kí o sì gba Kéílà sílẹ̀ Àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dáfídì sì wí fún un pé, Wò ó, àwa ń bẹ̀rù níhín yìí ní Júdà ǹjẹ́ yóò ti rí nígbà ti àwa bá dé Kéílà láti fi ojú ko ogun àwọn ara Fílístínì Dáfídì sì tún béèrè lọ́dọ Olúwa Olúwa sì dá a lóhùn, ó sì wí pé, Dìde, kí o sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kéílà, nítorí pé èmi ó fi àwọn ará Fílístínì náà lé ọ lọ́wọ́ Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Kéílà, wọ́n sì bá àwọn ará Fílístínì jà, wọ́n sì kó ohun ọ̀sìn wọn, wọ́n sì fi ìparun ńlá pa wọ́n Dáfídì sì gba àwọn ará Kéílà sílẹ̀ Ó sì ṣe, nígbà tí Ábíátarì ọmọ Áhímélékì fi sá tọ Dáfídì lọ ní Kéílà, ó sọ̀kalẹ̀ òun pẹ̀lú éfódù kan lọ́wọ́ rẹ̀ A sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé Dáfídì wá sí Kéílà Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́ nítorí tí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ ní ti wíwá tí ó wá sí ìlú tí ó ní ìlẹ̀kùn àti kẹrẹ Ṣọ́ọ̀lù sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kéílà, láti ká Dáfídì mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ Dáfídì sì mọ̀ pé Ṣọ́ọ̀lù ti gbèrò búburú sí òun ó sì wí fún Ábíátarì àlùfáà náà pé, Mú éfódù náà wá níhínìnyìí! Dáfídì sì wí pé, Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Ṣọ́ọ̀lù ń wá ọ̀nà láti wá sí Kéílà, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi Àwọn àgbà ìlú Kéílà yóò fi mí lé e lọ́wọ́ bí Ṣọ́ọ̀lù yóò hà sọ̀kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ bí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, èmi bẹ̀ ọ́, wí fún ìránṣẹ́ rẹ Olúwa sì wí pé, Yóò sọ̀kalẹ̀ wá Dáfídì sì wí pé, Àwọn àgbà ilú Kéílà yóò fi èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi lé Ṣọ́ọ̀lù lọ́wọ́ bí Olúwa sì wí pé, Wọn ó fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́ Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta ènìyàn sì dìdé, wọ́n lọ kúrò ní Kéílà, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ A sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Dáfídì ti sá kúrò ní Kéílà kò sì lọ sí Kéílà mọ́ Dáfídì sì ń gbé ní ihà, níbi tí ó ti sá pamọ́ sí, ó sì ń gbé níbi òkè-ńlá kan ní ihà Sífì Ṣọ́ọ̀lù sì ń wá a lójóojúmọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi lé e lọ́wọ́ Dáfídì sì ríi pé, Ṣọ́ọ̀lù ti jáde láti wá ẹ̀mi òun kiri Dáfídì sì wà ní ihà Sífì nínú igbó kan Jónátanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì dìde, ó sì tọ Dáfídì lọ nínú igbó náà, ó sì gbà á ní ìyànjú nípa ti Ọlọ́run Òun sì wí fún un pé, Má ṣe bẹ̀rù, nítorí tí ọwọ́ Ṣọ́ọ̀lù baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́ ìwọ ni yóò jọba lórí Ísírẹ́lì, èmi ni yóò sì ṣe ibìkejì rẹ Ṣọ́ọ̀lù baba mi mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn níwájú Olúwa Dáfídì sì jókòó nínú igbó náà Jónátanì sì lọ sí ilé rẹ̀ Àwọn ará Sífì sì gòkè tọ Ṣọ́ọ̀lù wá sí Gíbéà, wọ́n sì wí pé, Ṣé Dáfídì ti fi ara rẹ̀ pamọ̀ sọ́dọ̀ wa ní ibi gíga ìsápamọ́sí ní Hórésì, ní òkè Hákílà, tí ó wà níhà gúsù ti Jésímọ́nì Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Ọba, sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bi gbogbo ìfẹ́ tí ó wà ní ọkàn rẹ láti sọ̀kalẹ̀ ipa tí àwa ní láti fi lé ọba lọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, Alábùkún fún ni ẹ̀yin nípa Olúwa nítorí pé ẹ̀yin ti káàánú fún mi Lọ, èmi bẹ̀ yín, ẹ tún múra, kí ẹ sì mọ̀ ki ẹ si rí ibi tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ gbé wà, àti ẹni tí ó rí níbẹ̀ nítorí tí a ti sọ fún mi pé Ọgbọ́n ni ó ń lò jọjọ Ẹ sì wo, kí ẹ sì mọ ibi ìsápamọ́ tí ó máa ń sápamọ́ sí, kí ẹ sì tún padà tọ̀ mí wá, kí èmi lè mọ̀ dájú èmi ó sì bá yín lọ yóò sì ṣe bí ó bá wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, èmi ó sì wá a ní àwárí nínú gbogbo ẹgbẹ̀rún Júdà! Wọ́n sì dìde, wọ́n sì ṣáájú Ṣọ́ọ̀lù lọ sí Sífì ṣùgbọ́n Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní ihà Máónì, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níhà gúsù ti Jésímónì Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ ń wá a Wọ́n sì sọ fún Dáfídì ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí ibi òkúta kan, ó sì jókòó ní ihà ti Máónì Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́, ó sì lépa Dáfídì ní ihà Máónì Ṣọ́ọ̀lù sì ń rin apákan òkè kan, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní apákejì òkè náà Dáfídì sì yára láti sá kúrò níwájú Ṣọ́ọ̀lù nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti rọ̀gbà yí Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ká láti mú wọn Ṣùgbọ́n oníṣẹ́ kan sì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá ó sì wí pé, Ìwọ yára kí o sì wá, nítorí tí àwọn Fílístínì ti gbé ogun ti ilẹ̀ wa Ṣọ́ọ̀lù sì padà kúrò ní lilépa Dáfídì, ó sì lọ pàdé àwọn Fílístínì nítorí náà ni wọ́n sì ṣe ń pe ibẹ̀ náà ní òkúta ìpínyà Dáfídì sì gòkè láti ibẹ̀ lọ, ó sì jókòó níbi tí ó sápamọ́ sí ní Éńgédì Dáfídì Gé Etí Aṣọ Ṣọ́ọ̀lù Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù padà kúrò lẹ́yìn àwọn Fílístínì a sì sọ fún un pé, Wò ó, Dáfídì ń bẹ́ ni ihà Éńgédì Ṣọ́ọ̀lù sì mú ẹgbẹ̀ẹ́dógún akọni ọkùnrin tí a yàn nínú gbogbo Ísírẹ́lì ó sì lọ láti wá Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lorí òkúta àwọn ewúrẹ́ igbó Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Ṣọ́ọ̀lù sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹṣẹ̀ rẹ̀, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì wí fún un pé, Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí Olúwa wí fún ọ pé, Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ   Dáfídì sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Ṣọ́ọ̀lù Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dáfídì nítorí tí ó gé etí aṣọ Ṣọ́ọ̀lù Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, Èèwọ̀ ni fún mi láti ọdọ Olúwa wá bí èmi bá ṣe nǹkan yìí sí ẹni tí a ti fi àmì òróró Olúwa yàn, láti nawọ́ mi sí i, nítorí pé ẹni-àmì-òróró Olúwa ni Dáfídì sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ Dáfídì sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Ṣọ́ọ̀lù pé, Olúwa mi, ọba! Ṣọ́ọ̀lù sì wo ẹ̀yìn rẹ̀ Dáfídì sì dojú rẹ́ bọ ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un Dáfídì sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Èé ha ti ṣe tí ìwọ fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn pé, Wò ó, Dáfídì ń wa ẹ̀mí rẹ́ Wò ó, ojú rẹ́ ríi lónìí, bí Olúwa ti fi ìwọ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú ihò àwọn kan ní kí èmi ó pa ọ ṣùgbọ́n èmi dá ọ sí Èmi sì wí pé, èmi kì yóò nawọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni-àmì-òróró Olúwa ni òun jẹ́ Pẹ̀lúpẹ̀lú, baba mi, wò ó, àní wo etí aṣọ rẹ lọ́wọ́ mi nítorí èmi gé etí aṣọ rẹ, èmi kò sì pa ọ́, sì wò ó, kí o sì mọ̀ pé kò sí ibi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ń dọdẹ ẹ̀mi mi láti gbà á Kí Olúwa ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àti ìwọ, àti kí Olúwa ó gbẹ̀san mi lára rẹ ṣùgbọ́n, ọwọ́ mi kì yóò sí lara rẹ Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, ìwá-búburú a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn búburú jáde wá ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ Nítorí ta ni ọba Ísírẹ́lì fi jáde Ta ni ìwọ ń lépa Òkú ajá, tàbí eṣinṣin Kí Olúwa ó ṣe onídájọ́, kí ó sì dájọ́ láàrin èmi àti ìwọ, kí ó sì gbéjà mi, kí ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ Ó sì ṣe, nígbà tí Dáfídì sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, Ohùn rẹ ni èyí bí, Dáfídì ọmọ mi Ṣọ́ọ̀lù sì gbé ohùn rẹ̀ sòkè, o sunkún Ó sì wí fún Dáfídì pé, Ìwọ ṣe olódodo jù mí lọ nítorí pé ìwọ ti fi ire san án fún mi, èmi fi ibi san án fún ọ Ìwọ sì fi oore tí ìwọ ti ṣe fún mi hàn lónìí nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti fi èmi mi lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì pa mí Nítorí pé bí ènìyàn bá rí ọta rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní àlàáfíà bí Olúwa yóò sì fi ire san èyí ti ìwọ́ ṣe fún mi lónìí Wò ó, èmi mọ̀ nísinsin yìí pé, nítòótọ́ ìwọ ó jẹ ọba, àti pé ìjọba Ísírẹ́lì yóò sì fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ Sì búra fún mi nísinsin yìí ní orúkọ Olúwa , pé, ìwọ kì yóò gé irú ọmọ mi kúrò lẹ́yin mi, àti pé, ìwọ kì yóò pa orukọ mi run kúrò ní ìdílé baba mi Dáfídì sì búra fún Ṣọ́ọ̀lù Ṣọ́ọ̀lù sì lọ sí ilé rẹ̀ ṣùgbọ́n Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ sí ihò náà Nabali Kọ Lati Ran Dáfídì Lọ́wọ́ Sámúẹ́lì sì kú gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì sunkún rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ilé rẹ̀ ní Rama Dáfídì sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Páránì Ọkùnrin kan sì ń bẹ ní Máónì, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ń bẹ ní Kámẹ́lì ọkùnrin náà sì ní ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún ewúrẹ́ ó sì ń rẹ irun àgùntàn rẹ̀ ní Kámẹ́lì Orúkọ ọkùnrin náà sì ń jẹ́ Nábálì, orúkọ aya rẹ̀ ń jẹ́ Ábígáílì òun sì jẹ́ olóye obìnrin, àti arẹwà ènìyàn ṣùgbọ́n òǹrorò àti oníwà búburú ni ọkùnrin ẹni ìdílé Kálẹ́bù ni òun jẹ́ Dáfídì sì gbọ́ ní ihà pé Nábálì ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀ Dáfídì sì rán ọmọkùnrin mẹwàá, Dáfídì sì sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà pé, Ẹ gòkè lọ sí Kámẹ́lì, kí ẹ sì tọ Nábálì lọ, kí ẹ sì kí i ni orúkọ mi Báyìí ni ẹ ó sì wí fún ẹni tí ó wà ni ìrora pé, Àlàáfíà fún ọ! Àlàáfíà fún ohun gbogbo tí ìwọ ní!  Ǹjẹ́ mo gbọ́ pé, àwọn olùrẹ̀run ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ Wò ó, àwọn olùsọ́ àgùntàn rẹ ti wà lọ́dọ̀ wa àwa kò sì pà wọ́n lára, wọn kò sì sọ ohunkóhun nù ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà ní Kámẹ́lì Bi àwọn ọmọkùnrin rẹ léèrè, wọn ó sì sọ fún ọ Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí rí ojú rere lọ́dọ̀ rẹ nítorí pé àwa sá wá ní ọjọ́ àṣè èmi bẹ̀ ọ́ ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà, fi fún àwọn ìránṣe rẹ, àti fún Dáfídì ọmọ rẹ   Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì lọ, wọ́n sì sọ fún Nábálì gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní orúkọ Dáfídì, wọ́n sì sinmi Nábálì sì dá àwọn ìránṣẹ Dáfídì lóhùn pé, Ta ni ń jẹ́ Dáfídì Tàbí ta ni sì ń jẹ́ ọmọ Jésè Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iránṣe ni ń bẹ ni isinsinyìí tí wọn sá olúkúlùkù kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀ Ǹjẹ́ ki èmi o mú òunjẹ́ mi, àti omi mi, àti ẹran mi ti mo pá fún àwọn olùrẹ́run mi, ki èmi si fi fún àwọn ọkùnrin ti èmi kò mọ̀ ibi wọ́n ti wá Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì pada, wọ́n sì wá, wọn si rò fún un gẹ́gẹ́ bi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí Dáfídì sí wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, Kí olúkúlùkù yín ó di idá rẹ́ mọ́ idi, Olúkúlùkù ọkùnrin sì di idà tirẹ́ rẹ́ mọ̀ ìdí àti Dáfídì pẹ̀lú sì di idà tirẹ̀ ìwọ̀n irinwó ọmọkùnrin si gòkè tọ Dáfídì lẹ́yin igba si jókòó nibi ẹrù Ọkan nínú àwọn ọmọkùnrin Nabali si wí fún Ábígáílì aya rẹ̀ pé, Wo o, Dáfídì rán oníṣẹ́ láti ihà wá láti ki olúwa wa ó sì kanra mọ́ wọn Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà ṣe oore fún wa gidigidi, wọn kò ṣe wá ní ibi kan, ohunkóhun kò nù ni ọwọ́ wa ni gbogbo ọjọ́ ti àwa bá wọn rìn nígbà ti àwa ń bẹ lóko Odi ni wọ́n sáà jásí fún wa lọ́sànán, àti lóru, ni gbogbo ọjọ́ ti a fi bá wọn gbé, tí a n bojútó àwọn àgùntàn Ǹjẹ́, rò ó wò, kí ìwọ sì mọ èyí ti ìwọ yóò ṣe nítorí pé a ti gbèrò ibi sí olúwa wa, àti sí gbogbo ilé rẹ̀ òun sì jásí ọmọ Bélíálì tí a kò le sọ̀rọ̀ fún Ábígáílì sì yára, ó sì mú igba ìṣù àkàrà àti ìgò-ọtí wáìnì méjì, àti àgùntàn márùn-ún, ti a ti ṣè, àti oṣuwọn àgbàdo yíyan márùn-ún, àti ọgọ́rùn-ún ìdì àjàrà, àti igba àkàrà èso ọ̀pọ̀tọ́, ó sì dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Òun sì wí fún àwọn ọmọkùrin rẹ̀ pé, Má a lọ níwájú mi wò ó, èmi ń bọ̀ lẹ́yìn yín, Ṣùgbọ́n òun kò wí fún Nábálì baálé rẹ̀ Bí o ti gun orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sì ń sọ̀kalẹ̀ sí ibi ìkọ̀kọ̀ òkè náà, wò ó, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ níwájú rẹ̀ òun sì wá pàdé wọn Dáfídì sì ti wí pé, Ǹjẹ́ lásán ni èmi ti pa gbogbo èyi tí i ṣe ti eléyìí ní ihà, ti ohunkóhun kò sì nù nínú gbogbo èyí ti í ṣe tirẹ̀ òun ni o sì fi ibi san ire fún mi yìí Bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni ki Ọlọ́run ó ṣe sí àwọn ọ̀ta Dáfídì, bi èmi bá fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú gbogbo èyí tí i ṣe tirẹ̀ títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ Ábígáílì sì rí Dáfídì, ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú Dáfídì, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wí pé, Olúwa mi, fi ẹ̀ṣẹ̀ yìí yá mi kí ó sì jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, sọ̀rọ̀ létí rẹ, kí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ Olúwa mi, èmi bẹ̀ ọ́ má ka ọkùnrin Bélíálì yìí sí, àní Nábálì nítorí pé bí orúkọ rẹ̀ ti jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òun náà rí Nábálì ni orúkọ rẹ̀, àìmoye si wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́bìnrin rẹ kò ri àwọn ọmọkùnrin olúwa mi, ti ìwọ rán Ǹjẹ́ Olúwa mi, bi Olúwa ti wà láàyè, àti bí ẹ̀mí rẹ̀ si ti wà láàyè, bi Olúwa sì ti dá ọ dúró láti wá ta ẹ̀jẹ̀ silẹ̀, àti láti fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san ǹjẹ́, kí àwọn ọ̀ta rẹ, àti àwọn ẹni tí ń gbérò ibi sí olúwa mi rí bi Nábálì Ǹjẹ́ èyí ni ẹ̀bùn tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ mú wá fún olúwa mi, jẹ́ kí a sì fi fún àwọn ọmọkùnrin ti ń tọ olúwa mi lẹ́yìn Èmi bẹ̀ ọ́, fi ìrékọjá arábìnrin rẹ jìn ní nítorí Olúwa yóò fi ìdí ìjọba olúwa mi múlẹ̀, nítorí pé ó ja ogun Olúwa Nítorí náà kí a má ri ibi kan ni ọwọ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí ó wà láàyè Bí ọkùnrin kan bá sì dìde láti máa lépa rẹ, àti máa wá ẹ̀mí rẹ, a ó sì di ẹ̀mí olúwa mi mú láàyè lọdọ Olúwa Ọlọ́run rẹ àti ẹ̀mí àwọn ọ̀ta rẹ ni a ó sì gbọ̀n sọnù gẹ́gẹ́ bí kànnàkànnà jáde Yóò sì ṣe, Olúwa yóò ṣe sí olúwa mi gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìre tí ó ti wí nípa tirẹ̀, yóò sì yàn ọ́ ni aláṣẹ lórí Ísírẹ́lì Èyí kì yóò sì jásí ìbànújẹ fún ọ, tàbí ìbànújẹ́ ọkàn fún olúwa mi, nítorí pé ìwọ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, tàbí pé olúwa mi gbẹ̀san fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n nígbà tí Olúwa ba ṣe oore fún olúwa mi, ǹjẹ́ rántí ìránṣẹ́bìnrin rẹ! Dáfídì sì wí fún Ábígáílì pé, Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi Ìbùkún ni fún ọgbọ́n rẹ, alábùkún sì ni ìwọ, tí ó da mi dúró lónìí yìí láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ mi gbẹ̀san fún ara mi Nítòòtọ́ ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí ń bẹ, tí ó da mi dúró láti pa ọ́ lára bí kò ṣe pé bí ìwọ ti yára tí ó sì wá pàdé mi, nítòótọ́ kì bá tí kù fún Nábálì di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì gba nǹkan tí ó mú wá fún un lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, Gòkè lọ ni àlàáfíà sí ilé rẹ, wò ó, èmi ti gbọ́ ohùn rẹ, inú mi sì dùn sí ọ Ábígáílì sì tọ Nábálì wá, sì wò ó, òun sì ṣe àṣè ni ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àsè ọba inú Nábálì sì dùn nítorí pé, ó ti mú ọtí ni àmupara òun kò si sọ nǹkan fún un, díẹ̀ tàbí púpọ̀ títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ Ó sì ṣe ni òwúrọ̀, nígbà ti ọtí náà si dá tán lójú Nábálì, obìnrin rẹ̀ si ro nǹkan wọ̀nyí fún un, ọkàn rẹ sì kú nínú rẹ̀, òun sì dàbí òkúta Ó sì ṣe lẹ́yin ìwọ̀n ijọ mẹ́wàá, Olúwa lu Nábálì, ó sì kú Dáfídì sì gbọ́ pé Nábálì kú, ó sì wí pé, Ìyìn ni fún Olúwa tí o gbéjà gígàn mi láti ọwọ́ Nábálì wá, tí ó sì dá ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró láti ṣe ibi Olúwa sì yí ikà Nábálì sí orí òun tìkárarẹ̀ Dáfídì sì ránṣẹ́, ó sì ba Ábígáílì sọ̀rọ̀ láti mú un fi ṣe aya fún ara rẹ̀ Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì lọ sọ́dọ̀ Ábígáílì ni Kamẹ́lì, wọn sì sọ fún un pé, Dáfídì rán wá si ọ láti mu ọ ṣe aya rẹ̀ Ó sì dìde, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì wí pé, Wò ó, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ ó jẹ́ ìránṣẹ́ kan láti máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi Ábígáílì sì yára, ó sì dìde, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn iránṣẹ́bìnrin rẹ̀ márùnún sì tẹ̀lé e lẹ́yìn oun sì tẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, o sì wá di aya rẹ̀ Dáfídì sì mú Áhínóámù ará Jésírẹ́lì àwọn méjèèjì sì jẹ́ aya rẹ̀ Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ti fi Míkálì ọmọ rẹ̀ obìnrin aya Dáfídì, fún Fátíélì ọmọ Láìsi tí i ṣe ara Gálímù Dáfídì Tún Kọ̀ Láti Pa Ṣọ́ọ̀lù Nígbà náà ni àwọn ará Sífì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá sí Gíbéà, wọn wí pé, Dáfídì kò ha fi ara rẹ̀ pamọ́ níbi òkè Hákílà, èyí tí ó wà níwájú Jésímónì Ṣọ́ọ̀lù sì dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Sífì ẹgbẹ̀ẹ́dógún àṣàyàn ènìyàn ni Ísírẹ́lì sì pẹ̀lú rẹ̀ láti wá Dáfídì ni ijù Sífì Ṣọ́ọ̀lù sì pàgọ́ rẹ̀ ní ibi òkè Hákílà tí o wà níwájú Jésímónì lójú ọ̀nà, Dáfídì sì jókòó ni ibi ijù náà, ó sì rí pé Ṣọ́ọ̀lù ń tẹ̀lé òun ni ijù náà Dáfídì sì rán àyọ́lẹ̀wò jáde, ó sì mọ nítòótọ́ pé Ṣọ́ọ̀lù ń bọ̀ Dáfídì sì dìde, ó sì wá sí ibi ti Ṣọ́ọ̀lù pàgọ́ sí Dáfídì rí ibi tí Ṣọ́ọ̀lù gbé dúbúlẹ̀ sí, àti Ábínérì ọmọ Nérì, olórí ogun rẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù sì dùbúlẹ̀ láàrin àwọn kẹ̀kẹ́, àwọn ènìyàn náà sì pàgọ́ wọn yí i ká Dáfídì sì dáhùn, ó sì wí fún Áhímélékì, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hétì, àti fún Ábíṣáì ọmọ Sérúíà ẹ̀gbọ́n Jóábù, pé, Ta ni yóò ba mi sọ̀kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Ṣọ́ọ̀lù ni ibùdó Ábíṣáì sì wí pé, Èmi yóò ba ọ sọ̀kalẹ̀ lọ Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti Ábíṣáì sì tọ àwọn ènìyàn náà wá lóru sì wò ó, Ṣọ́ọ̀lù dùbúlẹ̀ ó sì ń sùn láàrin kẹ̀kẹ́, a sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ ni ibi tìmùtìmù rẹ̀ Ábínérì àti àwọn ènìyàn náà sì dùbúlẹ̀ yí i ká Ábíṣáì sì wí fún Dáfídì pé, Ọlọ́run ti fi ọ̀ta rẹ lé ọ lọ́wọ́ lónìí ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, ṣáà jẹ́ kí èmi o fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, èmi kì yóò gun un lẹ́ẹ̀méjì Dáfídì sì wí fún Ábíṣáì pé, Má ṣe pa á nítorí pé ta ni lè na ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni àmì-òróró Olúwa kí ó sì wà láìjẹ̀bi Dáfídì sì wí pé, Bí Olúwa tí ń bẹ Olúwa yóò pa á, tàbí ọjọ́ rẹ̀ yóò sì pé tí yóò kú, tàbí òun ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ìjà yóò sì ṣègbé níbẹ̀ Olúwa má jẹ́ kí èmi na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró Olúwa ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, mú ọ̀kọ̀ náà tí ń bẹ níbi tìmùtìmù rẹ̀, àti ìgò omi kí a sì máa lọ Dáfídì sì mú ọ̀kọ̀ náà àti ìgò omi náà kúrò níbi tìmùtìmù Ṣọ́ọ̀lù wọ́n sì bá tiwọn lọ, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí i, tàbí tí ó mọ̀ kò sì sí ẹnikàn tí ó jí gbogbo wọn sì sùn nítorí pé oorun ìjìká láti ọdọ Olúwa wá ti ṣubú lù wọ́n Dáfídì sì rékọjá sí ìhà kejì, ó sì dúró lórí òkè kan tí ó jìnnà réré àlàfo kan sì wà láàrin méjì wọn Dáfídì sì kọ sí àwọn ènìyàn náà àti sí Ábínérì ọmọ Nérì wí pé, Ìwọ kò dáhùn, Ábínérì Nígbà náà ni Ábínérì sì dáhùn wí pé, Ìwọ ta ni ń pe ọba Dáfídì sì wí fún Ábínérì pé, Alágbára ọkùnrin kọ́ ni ìwọ bí Ta ni ó sì dàbí ìwọ ni Ísírẹ́lì Ǹjẹ́ èéṣe tí ìwọ kò tọ́jú ọba Olúwa rẹ Nítorí ẹnìkan nínú àwọn ènìyàn náà ti wọlé wá láti pa ọba Olúwa rẹ Nǹkan tí ìwọ ṣe yìí kò dára Bí Olúwa ti ń bẹ, o tọ́ kí ẹ̀yin ó kú, nítorí pé ẹ̀yin kò pa olúwa yín mọ́, ẹni àmì òróró Olúwa Ǹjẹ́ sì wo ibi tí ọ̀kọ̀ ọba gbé wà, àti ìgò omi tí ó ti wà ní bi tìmùtìmù rẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù sì mọ ohùn Dáfídì, ó sì wí pé, Ohùn rẹ ni èyí bí Dáfídì ọmọ mi Dáfídì sì wí pé, Ohùn mi ni, Olúwa mi, ọba Òun sì wí pé, Nítorí kín ni Olúwa mi ṣe ń lépa ìránṣẹ́ rẹ̀ Kín ni èmi ṣe Tàbí ìwà búburú wo ni ó wà lọ́wọ́ mi Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, ọba, Olúwa mi, gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ Bí ó bá ṣe Olúwa bá ti rú ọ sókè sí mi, jẹ́ kí òun o gba ẹbọ ṣùgbọ́n bí o bá sì ṣe pé ọmọ ènìyàn ni, ìfibú ni kí wọn ó jásí níwájú Olúwa nítorí tí wọn lé mi jáde lónìí kí èmi má baà ní ìpín nínú ilẹ̀ ìní Olúwa , wí pé, Lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn Ǹjẹ́ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi ó ṣàn sílẹ̀ níwájú Olúwa nítorí ọba Ísírẹ́lì jáde láti wá ẹ̀mí mi bi ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè ńlá Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, Èmi ti dẹ́sẹ̀ yípadà, Dáfídì ọmọ mi nítorí pé èmi kì yóò wa ibi rẹ mọ́, nítorí tí ẹ̀mí mi sì ti ṣe ìyebíye lójú rẹ lónìí wò ó, èmi ti ń hùwà òmùgọ̀, mo sì ti ṣìnà jọjọ Dáfídì sì dáhùn, ó sì wí pé, Wò ó, ọ̀kọ̀ ọba! Kí ó sì jẹ́ kí ọkan nínú àwọn ọmọkùnrin rékọjá wá gbà á Kí Olúwa o san án fún olúkúlùkù bí òdodo rẹ̀ àti bí òtítọ́ rẹ̀ nítorí pé Olúwa tí fi ọ lé mi lọ́wọ́ lónìí, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ nawọ́ mi sí ẹni àmì òróró Olúwa Sì wò ó, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí rẹ ti tóbi lónìí lójú mi, bẹ́ẹ̀ ni ki ẹ̀mí mi ó tóbi lójú Olúwa , kí ó sì gbà mí lọ́wọ́ ibi gbogbo Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Dáfídì pé, Alábùkún fún ni ìwọ, Dáfídì ọmọ mi nítòótọ́ ìwọ yóò sì ṣe nǹkan ńlá, nítòótọ́ ìwọ yóò sì borí Dáfídì sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, Ṣọ́ọ̀lù sì yípadà sí ibùgbé rẹ̀ Dáfídì Sálọ Sí Ọ̀dọ̀ Ọba Fílístínì Kan Dáfídì sì wí ní ọkàn ara rẹ̀ pé, Ǹjẹ́ ni ìjọ kan ni èmi yóò ti ọwọ́ Ṣọ́ọ̀lù ṣègbé, kò sì sí ohun tí ó yẹ mí jù kí èmi yára sá àsálà lọ sórí ilẹ̀ àwọn Fílístínì yóò sú Ṣọ́ọ̀lù láti máa tún wa mi kiri ní gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì èmi a sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ Dáfídì sì dìde, ó sì rékọjá, òun pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí o ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sí Ákíṣì, ọmọ Máókì, ọba Gátì Dáfídì sì bá Ákíṣì jókòó ní Gátì, òun, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ, olúkúlùkù wọn pẹ̀lú ará ilé rẹ̀ Dáfídì pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, Áhínóámù ara Jésréélì, àti Ábígáílì ará Kámẹ́lì aya Nábálì A sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Dáfídì sá lọ si Gátì òun kò sì tún wá á kiri mọ́ Dáfídì sì wí fún Ákíṣì pé, Bí ó bá jẹ́ pé èmi rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí wọn ó fún mi ní ibìkan nínú àwọn ìletò wọ̀nyí èmi yóò máa gbé ibẹ̀ èéṣé tí ìránṣẹ́ rẹ yóò sì máa bá ọ gbé ní ìlú ọba Ákíṣì sí fi Síkílágì fún un ní ijọ́ náà nítorí náà ni Síkílágì fí dí ọba Júdà títí ó fí dì òní yìí Iye ọjọ́ tí Dáfídì fi jókòó ní ìlú àwọn Fílístínì sì jẹ́ ọdún kan àti oṣù mẹ́rin Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì gbé ogun ti àwọn ará Gésúrì, àti àwọn ara Gésírà, àti àwọn ará Ámálékì àwọn wọ̀nyí ni ó sì tí ń gbé ní ilẹ̀ náà, láti ìgbà àtijọ́, bí ó ti fẹ̀ lọ sí Ṣúrì títí ó fí dé ilẹ̀ Éjíbítì Dáfídì sì kọlu ilẹ̀ náà kò sì fi ọkùnrin tàbí obìnrin sílẹ̀ láàyè, ó sì kó àgùntàn, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ràkúnmí, àti aṣọ, ó sì yípadà ó tọ Ákíṣì wá Ákíṣì sì bi í pé, Níbo ni ẹ̀yin gbé rìn sí lónìí Dáfídì sì dáhùn pé, Síhà gúsù ti Júdà ni, tàbí Síhà gúsù ti Jérámélì, tàbí Síhà gúsù ti àwọn ará Kénì Dáfídì kò sì dá ọkùnrin tàbí obìnrin sí láàyè, láti mú ìròyìn wá sí Gátì, wí pé, Ki wọn máa bá à sọ ọ̀rọ̀ wa nibẹ̀, pé, Báyìí ni Dáfídì ṣe  Àti bẹ́ẹ̀ ni iṣe rẹ̀ yóò sì rí ni gbogbo ọjọ́ ti yóò fí jókòó ni ìlú àwọn Fílístínì Ákíṣì sì gba ti Dáfídì gbọ́, wí pé, Òun ti mú kí Ísírẹ́lì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ kóríra rẹ̀ pátapáta, yóò si jẹ́ ìránṣẹ́ mi títí láé Ṣọ́ọ̀lù Tọ Abókúsọ̀rọ̀ Lọ Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, àwọn Fílístínì sì kó àwọn ogun wọn jọ, láti bá Ísírẹ́lì jà Ákíṣì sì wí fún Dáfídì pé, Mọ dájúdájú pé, ìwọ yóò bá mi jáde lọ sí ibi ìjà, ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ Dáfídì sì wí fún Ákíṣì, pé, Nítòótọ́ ìwọ ó sì mọ ohun tí ìránṣẹ rẹ lè ṣe Ákíṣì sì wí fún Dáfídì pé, Nítorí náà ni èmi ó ṣe fi ìwọ ṣe olùṣọ́ orí mi ni gbogbo ọjọ́ Sámúẹ́lì sì ti kú, gbogbo Ísírẹ́lì sì sọkún rẹ̀, wọ́n sì sin ín ní Rámà ní ìlú rẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù sì ti mú àwọn abókúsọ̀rọ̀ ọkùnrin, àti àwọn abókúsọ̀rọ̀ obìnrin kúrò ní ilẹ̀ náà Àwọn Fílístínì sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣúnémù Ṣọ́ọ̀lù sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gílíbóà Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì rí ogun àwọn Fílístínì náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa , Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Úrímù tàbí nípa àwọn wòlíì Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mi abókúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀! Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, Wò ó, obìnrin kan wà ní Ẹ́ńdórì tí ó ní ẹ̀mí abókúsọ̀rọ̀ Ṣọ́ọ̀lù sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru òun sì wí pé, Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé Wò ó, ìwọ sáà mọ ohun tí Ṣọ́ọ̀lù ṣe, bí òun ti gé àwọn abókúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà ǹjẹ́ èé ha ṣe tí ìwọ dẹ́kùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí Ṣọ́ọ̀lù sì búra fún un nípa Olúwa pé, Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, ìyà kan kì yóò jẹ́ ọ́ nítorí nǹkan yìí Obìnrin náà sì bi í pé, Ta ni ẹ̀mí ó mú wá sókè fún ọ Òun sì wí pé, Mú Sámúẹ́lì gòkè wá fún mi Nígbà tí obìnrin náà sì rí Sámúẹ́lì, ó kígbe lóhùn rara obìnrin náà sì bá Ṣọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ pè, Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí jẹ Nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù ni ìwọ jẹ́ Ọba sì wí fún un pé, Má ṣe bẹ̀rù kín ni ìwọ rí Obìnrin náà sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Èmi rí ẹ̀mí kan tí ó ti ilẹ̀ wá Ó sì bi í pé, Báwo ni ó ti rí i sí Ó sì wí pé, Ọkùnrin arúgbó kan ni ó ń bọ ó sì fi agbádá bora Ṣọ́ọ̀lù sì mọ̀ pé, Sámúẹ́lì ni ó sì tẹríba, ó sì wólẹ̀ Sámúẹ́lì sì i wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Èéṣe tí ìwọ fi ń yọ mí lẹ́nu láti mú mi wá sókè Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn ó sì wí pé, Ìpọ́njú ńlá bá mi nítorí tí àwọn Fílístínì ń bá mi jagun, Ọlọ́run sì kọ̀ mí sílẹ̀, kò sì dá mi lóhùn mọ́, nípa ọwọ́ àwọn wòlíì, tàbí nípa àlá nítorí náà ni èmi ṣe pè ọ́, kí ìwọ lè fi ohun tí èmi yóò ṣe hàn mi Sámúẹ́lì sì wí pé, Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀ Olúwa sì ṣe fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ti ipa ọwọ́ mi sọ Olúwa sì yá ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi fún aládùúgbò rẹ́, àní Dáfídì Nítorí pé ìwọ kò gbọ́ ohùn Olúwa ìwọ kò sì ṣe iṣẹ́ ìbínú rẹ̀ sí Ámálékì nítorí náà ni Olúwa sì ṣe nǹkan yìí sí ọ lónìí yìí Olúwa yóò sì fi Ísírẹ́lì pẹ̀lú ìwọ lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́ ní ọ̀la ni ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò pẹ̀lú mi Olúwa yóò sì fi ogun Ísírẹ́lì lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́ Lojúkan náà ni Ṣọ́ọ̀lù ṣubú lulẹ̀ gbalaja ní bí ó ṣe gùn tó, ẹ̀rù sì bà á gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì agbára kò sí fún un nítorí pé kò jẹun ní ọjọ́ náà t'ọ̀sán t'òru Obìnrin náà sì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá, ó sì rí i pé ó wà nínú ìbànújẹ́ púpọ̀, ó sì wí fún un pé, Wò ó, ìránṣẹ́bìnrin rẹ́ ti gbọ́ ohun rẹ̀, èmi sì ti fi ẹ̀mi mi sí ọwọ́ mi, èmi sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ti ìwọ sọ fún mi Ǹjẹ́, nísinsìnyìí èmi bẹ̀ ọ́, gbọ́ ohùn ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi yóò sì fi oúnjẹ díẹ̀ ṣíwájú rẹ̀ sì jẹun, ìwọ yóò sì lágbára, nígbà tí ìwọ bá ń lọ lọ́nà Ṣùgbọ́n ó kọ̀, ó sì wí pé, Èmi kì yóò jẹun Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rọ̀ ọ́ Ó sì dide kúrò ni ilẹ̀, ó sì jókòó lorí àkéte Obìnrin náà sì ni ẹgbọrọ màlúù kan ti ó sańra ni ilé, ó sì yára, ó pa á, ó sì mú ìyẹ̀fún, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà àìwú Ó sì mú un wá ṣíwájú Ṣọ́ọ̀lù, àti ṣíwájú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ́n sì jẹun Wọ́n sì dìde, wọ́n lọ ní òru náà Ákíṣì Rán Dáfídì Sí Síkílágì Àwọn Fílístínì sì kó gbogbo ogun wọn jọ sí Áfékì Ísírẹ́lì sì dó ni ibi ìsun omi tí ó wà ní Jésírélì Àwọn ìjòyé Fílístínì sì kọjá ní ọ̀rọ̀ọ̀rún àti lẹ́gbẹgbẹ̀rún Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Ákíṣì sì kẹ́yìn Àwọn ìjòyé Fílístínì sì béèrè wí pé, Kín ni àwọn Hébérù ń ṣe nìhìn-ín yìí Ákíṣì sì wí fún àwọn ìjòyè Fílístínì pé Dáfídì kọ yìí, ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì, tí ó wà lọ́dọ̀ mi láti ọjọ́ wọ̀nyí tàbí láti ọdún wọ̀nyí, èmi kò ì tì í rí àṣìṣe kan ni ọwọ́ rẹ̀ lati ọjọ́ tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí Àwọn ìjòyé Fílístínì sì bínú sí i àwọn ìjòyé Fílístínì sì wí fún un pé, Jẹ́ kí ọkùnrin yìí padà kí ó sì lọ sí ipó rẹ̀ tí ó fi fún un, kí ó má sì jẹ́ kí ó bá wa sọ̀kalẹ̀ lọ sí ogun, kí ó má ba à jásí ọ̀ta fún wa ni ogun Kín ni òun ó fi ba olúwa rẹ̀ làjà, orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọ́ Ṣé èyí ni Dáfídì ti wọn torí rẹ̀ gberin ara wọn nínú ìjọ wí pé,  Ṣọ́ọ̀lù pa ẹgbẹgbẹrun rẹ̀, Dáfídì si pa ẹgbẹgbàárun tirẹ́   Ákíṣì sì pe Dáfídì, ó sì wí fún un pé, Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, ìwọ jẹ́ ólóòótọ́ àti ẹni ìwà rere lójú mi, ní àlọ rẹ àti ààbọ̀ rẹ pẹ̀lú mi ní ogun nítorí pé èmi ko tìí ri búburú kan lọ́wọ́ rẹ́ láti ọjọ́ ti ìwọ ti tọ̀ mí wá, títí o fi dì òní yìí ṣùgbọ́n lójú àwọn ìjòyè, ìwọ kò ṣe ẹni tí ó tọ́ Ǹjẹ́ yípadà kí o sì máa lọ ní àlàáfíà, kí ìwọ má ṣe bà àwọn Fílístínì nínú jẹ́ Dáfídì sì wí fún Ákíṣì pé, Kín ni èmi ṣe Kín ni ìwọ sì rí lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ láti ọjọ́ ti èmi ti ń gbé níwájú rẹ títí di òní yìí, tí èmi kì yóò fi lọ bá àwọn ọ̀ta ọba jà Ákíṣì sì dáhùn, ó sì wí fún Dáfídì pé, Èmi mọ̀ pé ìwọ ṣe ẹni-rere lójú mi, bi ańgẹ́lì Ọlọ́run ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Fílístínì wí pé, Òun kì yóò bá wa lọ sí ogun Ǹjẹ́, nísinsin yìí dìde ní òwúrọ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ tí ó bá ọ wá ki ẹ si dìde ní òwúrọ̀ nígbà tí ilẹ̀ bá mọ́ kí ẹ sì máa lọ Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì dìde ní òwúrọ̀ láti padà lọ sí ilẹ̀ àwọn Fílístínì Àwọn Fílístínì sì gòkè lọ sí Jésírélì Sámúẹ́lì ọmọkùnrin náà ṣe òjíṣẹ́ níwájú Olúwa ní abẹ́ Élì Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ọ̀rọ̀ Olúwa ṣọ̀wọ́n kò sì sí ìran púpọ̀ Ní alẹ́ ọjọ́ kan Élì ẹni tí ojú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí di aláìlágbára, tí kò sì ríran dáadáa, ó dùbúlẹ̀ ní ipò rẹ̀ bi ti àtẹ̀yìn wá Nígbà tí iná kò tí ì kú Sámúẹ́lì dùbúlẹ̀ nínú tẹ́ḿpìlì Olúwa , níbi tí àpótí Olúwa gbé wà Nígbà náà ni Olúwa pe Sámúẹ́lì Sámúẹ́lì sì dáhùn Èmi nìyí Ó sì sáré lọ sí ọ̀dọ̀ Élì ó sì wí pé, Èmi nìyí nítorí pé ìwọ pè mí Ṣùgbọ́n Élì wí fún-un pé, Èmi kò pè ọ́ padà lọ dùbúlẹ̀ Nítorí náà ó lọ ó sì lọ dùbúlẹ̀ Olúwa sì tún pè é, Sámúẹ́lì! Sámúẹ́lì tún dìde ó tọ Élì lọ, ó sì wí pé, Èmi nì yí, nítorí tí ìwọ pè mí Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀ Ní àkókò yìí Sámúẹ́lì kò tíì mọ̀ Olúwa bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án Olúwa pe Sámúẹ́lì ní ìgbà kẹ́tà, Sámúẹ́lì sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Élì ó sì wí pé, Èmi nì yí nítorí tí ìwọ pè mí Nígbà náà ni Élì wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà Nítorí náà Élì sọ fún Sámúẹ́lì, Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀ Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, máa wí, Olúwa nítorí tí ìrànṣẹ́ rẹ ń gbọ́   Bẹ́ẹ̀ ni Sámúẹ́lì lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀ Olúwa wá, ó sì dúró níbẹ̀, ó pè é bí ó ṣe pè é ní ìgbà tí ó kọjá, Sámúẹ́lì! Sámúẹ́lì! Nígbà náà ni Sámúẹ́lì dáhùn pé, Má a wí nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́ Olúwa sọ fún Sámúẹ́lì pé, Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Ísírẹ́lì tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Élì ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun Nítorí náà, mo búra sí ilé Élì, Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Élì ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé   Sámúẹ́lì dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì sí ìlẹ̀kùn ilé Olúwa , ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Élì Ṣùgbọ́n Élì pè é, ó sì wí pé, Sámúẹ́lì, ọmọ mi Sámúẹ́lì sì dáhùn pé, Èmi nìyìí Élì béèrè pé, Kín ni ohun tí ó sọ fún ọ  Má ṣe fi pamọ́ fún mi Kí Olúwa mi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ bá fi ohunkóhun tí ó wí fún ọ pamọ́ fún mi Sámúẹ́lì sọ gbogbo rẹ̀ fún un, kò sì fi ohun kankan pamọ́ fún un Nígbà náà Élì wí pé, Òun ni Olúwa jẹ́ kí ó ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀ Olúwa wà pẹ̀lú Sámúẹ́lì bí ó ṣe ń dàgbà, kò sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kùnà Gbogbo Ísírẹ́lì láti Dánì títí dé Bíáṣébà mọ̀ pé a ti fa Sámúẹ́lì kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì Olúwa Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ara hàn-án ní Ṣílò, nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Dáfídì Pa Gbogbo Àwọn Ámálékì Ó sì ṣe nigbà ti Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì bọ̀ sí Síkílágì ní ọjọ́ kẹta, àwọn ará Ámálékì sì ti kọlu Néséfà, àti Síkílágì, wọ́n sì ti kùn ún ní iná Wọ́n sì kó àwọn obìnrin tí ń bẹ nínú rẹ̀ ní ìgbékùn, wọn kò sì pa ẹnìkan, ọmọdé tàbí àgbà, ṣùgbọ́n wọ́n kó wọn lọ, wọ́n sì bá ọ̀nà tiwọn lọ Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin sì wọ ìlú, sì wò ó, a ti kun ún ni iná àti obìnrin wọn, àti ọmọkùnrin wọn àti ọmọbinrin wọn ni a kó ni ìgbèkùn lọ Dáfídì àti àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún títí agbára kò fi sí fún wọn mọ́ láti sunkún A sì kó àwọn aya Dáfídì méjèèjì nígbèkùn lọ, Áhínóámù ará Jésírẹ́lì àti Ábígáílì aya Nábálì ará Kámélì Dáfídì sì banújẹ́ gidigidi, nítorí pé àwọn ènìyàn náà sì ń sọ̀rọ̀ láti sọ ọ́ lókúta, nítorí ti inú gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bàjẹ́, olúkúlùkù ọkùnrin nítori ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti nítorí ọmọ rẹ̀ obìnrin ṣùgbọ́n Dáfídì mu ara rẹ̀ lọ́kàn le nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ Dáfídì sì wí fún Ábíátárì àlùfáà, ọmọ Áhímélékì pé, èmí bẹ̀ ọ́, mú éfódù fún mi wá níhín-ín yìí Ábíátarì sì mú éfódù náà wá fún Dáfídì Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa wí pé, Kí èmi ó lépa ogun yìí bi Èmi lè bá wọn Ó sì dá a lóhùn pé, Lépa nítorí pé ni bíbá ìwọ yóò bá wọn, ni gbígbà ìwọ yóò sì rí wọn gbà Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti ẹgbẹ̀tà ọmọkùnrin tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wá sí ibi ọ̀dọ̀ Bésórì, apákan sì dúró Ṣùgbọ́n Dáfídì àti irínwó ọmọkùnrin lépa wọn igba ènìyàn tí àárẹ̀ mú, ti wọn kò lè kọjá odò Bésórì sì dúró lẹ́yìn Wọ́n sì rí ara Éjíbítì kan ní oko, wọ́n sì mú un tọ Dáfídì wá, wọ́n sì fún un ní oúnjẹ, ó sì jẹ wọ́n sì fún un ní omi mu Wọ́n sì fún un ní àkàrà, èso ọ̀pọ̀tọ́ àti ṣírí àjàrà gbígbẹ́ méjì nígbà tí ó sì jẹ ẹ́ tán, ẹ̀mí rẹ̀ sì ṣojí nítorí pé kò jẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi ní ijọ́ mẹ́ta ní ọ̀sán, àti ní òru Dáfídì sì bi í léèrè pé, Ọmọ ta ni ìwọ Àti níbo ni ìwọ ti wá Òun sì wí pé, Ọmọ ará Éjíbítì ni èmi, ọmọ-ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan ará Ámálékì Olúwa mi fi mí sílẹ̀, nítorí pé láti ijọ́ mẹ́ta ni èmi ti ṣe àìsàn Àwa sì gbé ogun lọ síhà Gúúsù tí ara Kérítì, àti sí ìhà ti Júdà, àti sí ìhà Gúúsù ti Kélẹ́bù àwa sì kun Síkílágì ní iná Dáfídì sì bi í léèrè pé, Ìwọ lè mú mí sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun yìí lọ bí Òun sì wí pé, Fi Ọlọ́run búra fún mi pé, ìwọ kì yóò pa mí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò sì fi mi lé olúwa mi lọ́wọ́ èmi yóò sì mú ọ sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun náà lọ Ó sì mú un sọ̀kalẹ̀, sì wò ó, wọ́n sì tàn ká ilẹ̀, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ìkógun púpọ̀ tí wọ́n kó láti ilẹ̀ àwọn Fílístínì wá, àti láti ilẹ̀ Júdà Dáfídì sì pa wọ́n láti àfẹ̀mọ́júmọ́ títí ó fi di àṣálẹ́ ijọ́ kejì kò sí ẹnìkan tí ó là nínú wọn, bí kọ̀ ṣe irínwó ọmọkùnrin tí wọ́n gun ràkúnmí tí wọ́n sì sá Dáfídì sì gbà gbogbo nǹkan tí àwọn ará Ámálékì ti kó Dáfídì sì gba àwọn obìnrin rẹ̀ méjèèjì Kò sì sí nǹkan tí ó kù fún wọn, kékeré tàbí ńlá, ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin, tàbí ìkógun, tàbí gbogbo nǹkan tí wọ́n ti kó Dáfídì sì gba gbogbo wọn Dáfídì sì kó gbogbo àgùntàn, àti màlúù tí àwọn ènìyàn rẹ̀ dà ṣáàjú àwọn ohun mìíràn tí wọ́n gbà, wọ́n sì wí pé, Èyí yìí ni ìkógun ti Dáfídì Dáfídì sì wá sọ́dọ̀ igba ọkùnrin tí àárẹ̀ ti mú jú, ti wọn kò lè tọ́ Dáfídì lẹ́yin mọ́, ti òun ti fi sílẹ̀, ni odò Bésórì wọ́n sì lọ pàdé Dáfídì, àti láti pàdé àwọn ènìyàn tí ó lọ pẹ̀lú rẹ̀ Dáfídì sì pàdé àwọn ènìyàn náà, ó sì kí wọn Gbogbo àwọn ènìyàn búburú àti àwọn ọmọ Bélíálì nínú àwọn tí o bá Dáfídì lọ sì dáhùn, wọ́n sì wí pé, Bí wọn kò ti bá wa lọ, àwa ki yóò fi nǹkan kan fún wọn nínú ìkógun ti àwa rí gbà bí kò ṣe obìnrin olúkúlùkù wọn, àti ọmọ wọn ki wọn sì mú wọn, ki wọn sì máa lọ Dáfídì sì wí pé, Ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ara mi Olúwa ni ó fi nǹkan yìí fún wa, òun ni ó sì pa wá mọ́, òun ni ó sì fi ẹgbẹ́-ogun ti ó dìde sí wa lé wa lọ́wọ́ Ta ni yóò gbọ́ tiyín nínú ọran yìí Ṣùgbọ́n bi ìpín ẹni tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ si ìjà ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ti ó dúró ti ẹrù wọn ó sì pín in bákan náà Lati ọjọ́ náà lọ, ó sì pàṣẹ, ó sì sọ ọ di òfin fún Ísírẹlì títí di òní yìí Dáfídì sì padà sí Síkílágì, ó sì rán nínú ìkógun náà si àwọn àgbà Júdà, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì wí pé, Wò ó, èyí ni ẹ̀bùn fún un yín, láti inú ìkógun àwọn ọ̀ta Olúwa wa Ó sì rán an sí àwọn tí ó wà ni Bẹ́tẹ́lì àti sí àwọn tí ó wà ní Gúúsù tí Rámótì, àti sí àwọn tí ó wà ní Játírì Àti sí àwọn tí ó wà ní Áróérì, àti sí àwọn tí ó wà ní Sífímótì, àti sí àwọn tí ó wà ni Ésítémóà Àti si àwọn tí ó wà ni Rákélì, àti sí àwọn tí ó wà ní ìlú àwọn Jérámélì, àti sí àwọn tí ó wà ni ìlú àwọn ará Kéni Àti sí àwọn tí ó wà ni Hórímà, àti àwọn ti ó wà ní Kórásánì, àti sí àwọn tí ó wà ni Átakì Àti àwọn tí ó wà ni Hébírónì, àti sí gbogbo àwọn ilú ti Dáfídì tìkárarẹ̀ àti tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa ń rìnká Ṣọ́ọ̀lù Pa Ara Rẹ̀ Àwọn Fílístínì sì bá Ísírẹ́lì jà àwọn ọkùnrin Ísírẹlì sì sá níwájú àwọn Fílístínì, àwọn tí ó fi ara pa sì ṣubú ní òkè Gílíbóà Àwọn Fílístínì sì ń lépa Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ kíkan àwọn Fílístínì sì pa Jónátanì àti Ábínádábù, àti Mélíkísúà, àwọn ọmọ Ṣọ́ọ̀lù Ìjà náà sì burú fún Ṣọ́ọ̀lù gidigidi, àwọn tafàtafà si ta á ní ọfà, o sì fi ara pa púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn tafàtafà Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún ẹni tí o ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, Fa idà rẹ yọ, kí ìwọ sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má ba à wá gún mi, àti kí wọn kí ó má bá à fi mí ṣe ẹlẹ́yà Ṣùgbọ́n ẹni tí ó rú ẹ̀rù ìhámọ́ra rẹ̀ kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹ̀rù bà á gidigidi Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù mú idà, ó sì ṣubú lù ú Nígbà tí ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ si ríi pé Ṣọ́ọ̀lù kú, òun náà sì fi idà rẹ̀ pá ara rẹ̀, ó sì kú pẹ̀lú rẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù sì kú, àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta, àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọkùrin rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà Nígbà ti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó wà lápa kejì àfonífojì náà, àti àwọn ẹni tí ó wà lápá kejì Jódánì, rí pé àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sá, àti pé Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ ti kú, wọ́n sì fí ìlú sílẹ̀, wọ́n sì sá, àwọn Fílístínì sí wá, wọ́n sì jókòó si ìlú wọn Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn Fílístínì dé láti bọ́ nǹkán tí ń bẹ lára àwọn tí ó kù, wọ́n sì rí pé, Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta ṣubú ni òkè Gílíbóà Wọ́n sì gé orí rẹ̀, wọ́n sì bọ ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì ránṣẹ́ lọ ilẹ̀ Fílístínì káàkiri, láti máa sọ ọ́ nígbángba ni ilé òrìṣà wọn, àti láàrin àwọn ènìyàn Wọ́n sì fi ìhámọ́ra rẹ̀ sí ilé Áṣítárótì wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ odi Bétísánì Nígbà tí àwọn ará Jabesi-Gílíádì sì gbọ́ èyí tí àwọn Fílístínì ṣe sí Ṣọ́ọ̀lù Gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára sì dìde, wọ́n sì fi gbogbo òru náà rìn, wọ́n sì gbé òkú Ṣọ́ọ̀lù, àti okú àwọn ọmọ bibi rẹ̀ kúrò lára odi Bétísánì, wọ́n sì wá sí Jábésì, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀ Wọ́n sì kó egungun wọn, wọ́n sì sin wọ́n lábẹ́ igi kan ní Jábésì, wọ́n sì gba ààwẹ̀ ní ijọ́ méje Àwọn Fílístínì Gba Àpótí ẹ̀rí Ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì tọ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá Nísinsìnyìí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde láti lọ bá àwọn Fílístínì jà Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì pàgọ́ sí Ebenésérì àti àwọn Fílístínì ní Áfékì Àwọn Fílístínì mú ogun wọn sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Ísírẹ́lì, nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Fílístínì ṣẹ́gun Ísírẹ́lì wọ́n pa ẹgbàájì ọkùnrin nínú ogun náà Nígbà tí àwọn ọmọ ogun náà padà sí ibùdó, àwọn àgbà Ísírẹ́lì sì béèrè pé, Èéṣe ti Olúwa fi mú kí àwọn Fílístínì ṣẹ́gun wa lónìí Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa láti Ṣílò wá, kí ó ba à le lọ pẹ̀lú wa kí ó sì gbàwá là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wa Nítorí náà a rán àwọn ènìyàn lọ sí Ṣílò, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn ọmọ ogun wá, ẹni tí ń wà láàrin àwọn Kérúbù àti àwọn ọmọ Élì méjèèjì Hófínì àti Fínéhásì wà níbẹ̀ pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Nígbà tí àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa wá sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dìde láti kígbe tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ sì mì tìtì Ní ìgbà tí àwọn Fílístínì gbọ́ ariwo náà wọ́n béèrè pé, Kí ni gbogbo ariwo yìí ní ibùdó Hébérù Nígbà tí wọ́n mọ̀ wí pé àpótí ẹ̀rí Olúwa ti wá sí ibùdó, Àwọn Fílístínì sì bẹ̀rù pé, Ọlọ́run kékeré ti wọ ibùdó, wọ́n wí pé, A wọ wàhálà, irú èyí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí Àwa gbé! Ta ni yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ Ọlọ́run alágbára yìí Àwọn ni Ọlọ́run tí ó fi ìpọ́njú pa àwọn ará Éjíbítì pẹ̀lú gbogbo àjàkálẹ̀-àrùn ní ihà Ẹ jẹ́ alágbára Fílístínì, ẹ ṣe bí ọkùnrin, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin yóò di ẹrú àwọn Hébérù, bí wọ́n ti jẹ́ sí i yín Ẹ jẹ́ alágbára ọkùnrin, kí ẹ sì jagun! Nígbà náà àwọn Fílístínì jà, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn Ísírẹ́lì olúkúlùkù sì sá padà sínú àgọ́ rẹ̀, wọ́n pa ọ̀pọ̀ ènìyàn Àwọn ará Ísírẹ́lì tí ó kú sí ogun sì jẹ́ ẹgbàámẹ́ẹ̀ẹ́dógún àwọn ọmọ ogun orí ilẹ̀ Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí Olúwa , àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì sì kú, Hófínì àti Fínéhásì Lọ́jọ́ kan náà tí ará Bẹ́ńjámínì kan sá wá láti ojú ogun tí ó sì lọ sí Ṣílò, aṣọ rẹ̀ sì fàya pẹ̀lú eruku lórí rẹ̀ Nígbà tí ó sì dé, Élì sì jókòó sórí àga rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, ó ń wò, ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí àpótí ẹ̀rí Olúwa Nígbà tí ọkùnrin náà wọ ìlú tí ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, gbogbo ìlú bẹ̀rẹ̀ sí sunkún Élì gbọ́ ìró ohùn ẹkún náà ó sì béèrè pé, Kí ni ìtúmọ̀ ariwo yìí Ọkùnrin náà sì sáré tọ Élì wá ẹni tí ó jẹ́ ẹni méjìdínlọ́gọ́run ọdún, tí ojú rẹ̀ kò sì ríran mọ́ Ọkùnrin náà sọ fún Élì, Mo ṣẹ̀ ṣẹ̀ dé láti ibi ogun náà ni mo sá láti ibi ogun náà wá lónìí Élì sì béèrè pé, Kí ni ó ṣẹlẹ̀ ọmọ mi Ọkùnrin tí ó mú ìròyìn náà wá dáhùn pé, Ísírẹ́lì sá níwájú àwọn Fílístínì, àwọn ọmọ ogun náà sì kú lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ méjèèjì, Hófínì àti Fínéhásì, wọ́n kú, wọ́n sì ti gba àpótí ẹ̀rí Olúwa lọ Nígbà tí ó dárúkọ àpótí ẹ̀rí Olúwa , Élì sì ṣubú sẹ́yìn kúrò lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ bodè, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí tí ó jẹ́ arúgbó ọkùnrin, ó sì tóbi, ó ti darí àwọn Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún Aya ọmọ rẹ̀, ìyàwó Fínéhásì, ó lóyún ó súnmọ́ àkókò àti bí Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn náà wí pé wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Olúwa lọ àti wí pé baba ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ ti kú, ó rọbí ó sì bímọ, ó sì borí ìrora ìrọbí náà Bí ó ti ń kú lọ, obìnrin tí ó dúró tì í wí pé, má ṣe bẹ̀rù nítorí o ti bí ọmọ ọkùnrin Ṣùgbọ́n kò sọ̀rọ̀ tàbí kọ ibi ara sí i Ó sì pe ọmọ náà ní Íkábódù, wí pé, Kò sí ògo fún Ísírẹ́lì mọ́ nítorí tí wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àti ikú baba ọkọ rẹ̀ àti ti ọkọ rẹ̀ Ó si wí pé, Ogo kò sí fún Isirẹli mọ́, nítorí ti a ti gbá àpótí Ọlọ́run Àpótí Ẹ̀rí Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn Fílístínì ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ, wọ́n gbé e láti Ebenésérì sí Ásídódù Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí náà lọ sí Tẹ́ḿpìlì Dágónì, wọ́n gbé e kalẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ Dágónì Nígbà tí àwọn ará Ásídódù jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dágónì ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí Olúwa , wọ́n sì gbé Dágónì, wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀ Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dágónì sì wá, ó ṣubú ó dojú bolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù Ìdí nìyìí títí di òní tí ó fi jẹ́ pé àlùfáà Dágónì tàbí àwọn mìíràn tí ó wo inú tẹ́ḿpìlì Dágónì ní Ásídódù fi ń tẹ orí ìloro ẹnu ọ̀nà Ọwọ́ Olúwa wúwo lára àwọn ènìyàn Ásídódù àti gbogbo agbègbè rẹ̀ ó mú ìparun wá sórí wọn, ó sì pọ́n wọn lójú pẹ̀lú àrùn oníkókó Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ásídódù rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé, Àpótí ẹ̀rí Olúwa ti Ísírẹ́lì kò gbọdọ̀ dúró níbí yìí pẹ̀lú wa, nítorí ọwọ́ rẹ̀ wúwo lára wa àti lára Dágónì ọlọ́run wá Nígbà náà ni wọ́n pè gbogbo àwọn olórí Fílístínì jọ wọ́n sì bi wọ́n pé, Kí ni a ó ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn Ísírẹ́lì Wọ́n dáhùn pé, Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn Ísírẹ́lì lọ sí Gátì Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti gbé e, ọwọ́ Olúwa sì wá sí ìlú náà, ó mú jìnnìjìnnì bá wọn Ó sì pọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà lójú, ọmọdé àti àgbà, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn oníkókó Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ sí Ékírónì Bí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ṣe wọ Ékírónì, àwọn ará Ékírónì fi igbe ta pé, Wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì tọ̀ wá wá láti pa wá àti àwọn ènìyàn wa Nígbà náà ni wọ́n pe gbogbo àwọn olórí àwọn Fílístínì jọ wọ́n sì wí pé, Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì lọ ẹ jẹ́ kí ó padà sí àyè rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò pa wá àti àwọn ènìyàn wa Ikú ti mú jìnnìjìnnì bá àwọn ará ìlú ọwọ́ Ọlọ́run sì wúwo lára wọn Àwọn tí kò kú wọ́n pọ́n wọn lójú pẹ̀lú àrùn oníkókó, ẹkún ìlú náà sì gòkè lọ sí ọ̀run Àpótí Ẹ̀rí Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wà ní agbègbè Fílístínì fún oṣù méje, àwọn ará Fílístínì pe àwọn àlùfáà, àti àwọn aláṣọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì sọ pé, Kí ni kí a ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa Sọ fún wa bí àwa yóò ti dá a padà sí àyè rẹ̀ Wọ́n dáhùn wí pé, Tí ẹ bá dá àpótí ẹ̀rí Olúwa ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà, ẹ má ṣe dá a padà ní òfìfo, ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ẹ fún un ní ẹbọ ẹ̀bi Nígbà náà ni a ó mú un yín láradá, ẹ̀yin yóò sì mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ kò fi tí ì kúrò lára yín Àwọn ará Fílístínì béèrè pé, Irú ẹbọ ẹ̀bi wo ni kí a fi fún un Wọ́n dáhùn, Góòlù oníkókó márùn ún àti eku ẹ̀lírí wúrà márùn ún, gẹ́gẹ́ bí iye awọn aláṣẹ Fílístínì, nítorí àjàkálẹ̀-àrùn kan náà ni ó kọlù yín àti olórí yín Mọ àwòrán àrùn oníkókó àti ti eku èlírí yin tí ó ń ba orílẹ̀ èdè náà jẹ́ kí o sì bu ọlá fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Bóyá yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára yín, lára ọlọ́run yín àti lára ilẹ̀ yín Kí ni ó dé tí ẹ fi ń ṣé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Éjíbítì àti Fáráò ti ṣe Nígbà tí ó fi ọwọ́ líle mú wọn, ṣe wọn kò rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kí wọn kí ó lè lọ ní ọ̀nà wọn Nísinsìnyìí ẹ pèse kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun sílẹ̀, pẹ̀lú màlúù méjì tí ó ti fí ọmú fun ọmọ, èyí tí a kò tí ì fi ru ẹrù rí, kí ẹ sì so ó mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì mú ọmọ wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn wá sí ilé láti so Kí ẹ sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí orí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kí ẹ̀yin sì kó àwọn ohun èlò wúrà tí ẹ̀yin fi fún un gẹ́gẹ́ bí ti ẹbọ ẹ̀bi sí inú àpótí ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó sì rán an lọ, ṣùgbọ́n kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ Tí ó bá ń lọ sí ilẹ̀ rẹ̀, ìlú rẹ̀, níhà Bẹti-Sémésì Nígbà náà ni Olúwa mú àjálù ńlá yìí bá wa Ṣùgbọ́n bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà ni a mọ̀ pé kì í ṣe ọwọ́ rẹ̀ ni ó kọ lù wá, ṣùgbọ́n ó wá bẹ́ẹ̀ ni Nígbà náà ni wọ́n ṣe èyí Wọ́n mú abo màlúù méjì, tí ń fi ọmú fún ọmọ, wọn mọ́ ara, wọ́n sì dèé ni ilé kẹ̀kẹ́ ẹrù, wọn sì so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ ni ilé Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé orí kẹ̀kẹ́ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni àpótí tí eku ẹ̀lírí wúrà àti àwòrán àrùn oníkókó wà níbẹ̀ Nígbà náà àwọn màlúù lọ tààrà sí ìhà Béti-Ṣémésì, wọ́n ń lọ tààrà, wọ́n sì ń dún bí wọ́n ti ń lọ Wọn kò yà sí ọ̀tún tàbí yà sí òsì Àwọn aláṣẹ Fílístínì tẹ̀lé wọn títí dé ibodè Bẹti-Sémésì Nísinsìn yìí, àwọn ará Bẹti-Sémésì ń kórè jéró wọn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọ́n wo òkè tí wọ́n sì rí àpótí ẹ̀rí Olúwa , wọ́n yọ̀ níwájú rẹ̀ Kẹ̀kẹ̀ ẹrù wá sí pápá Jóṣúà ti Bẹti-Sémésì, níbẹ̀ ni ó ti dúró ní ẹ̀bá àpáta ńlá kan Àwọn ènìyàn gé igi ara kẹ̀kẹ́ ẹrù sí wẹ́wẹ́ wọ́n sì fi àwọn màlúù náà rúbọ sísun sí Olúwa Àwọn ará Léfì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ìṣàlẹ̀ pẹ̀lú àpótí tí ohun èlò wúrà wà níbẹ̀, wọ́n sì gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà Ní ọjọ́ náà, àwọn ará Bẹti-Sémésì rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ṣe ìrúbọ sí Olúwa Àwọn aláṣẹ Fílístínì márààrún rí gbogbo èyí, wọ́n sì padà ní ọjọ́ náà sí Ékírónì Èyí ni kókó wúrà tí àwọn Fílístínì fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀bi ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Ásídódù, ọ̀kan ti Gásà, ọ̀kan ti Ásíkélónì, ọ̀kan ti Gátì, ọ̀kan ti Ékírónì Góòlù eku-ẹ̀lírí jẹ́ iye ìlú tí àwọn aláṣẹ Fílístínì márààrún ti wá, ìlú olodi pẹ̀lú ìlétò wọn Àpáta ńlá náà, lórí èyí tí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé jẹ́ ẹ̀rí títí di òní ní oko Jóṣúà ará Bẹti-Sémésì Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọ lu díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin Bẹti-Sémésì, ó pa àádọ́rin wọn, nítorí wọ́n ti wo inú àpótí ẹ̀rí Olúwa Àwọn ènìyàn ṣọ̀fọ̀ nítorí àjálù ńlá tí Olúwa fi bá ọ̀pọ̀ wọn jà Àwọn ọkùnrin ará Bẹti-Sémésì béèrè pé, Ta ni ó le è dúró ní iwájú Olúwa Ọlọ́run mímọ́ yìí Ọ̀dọ̀ ta ni àpótí ẹ̀rí Olúwa yóò gbà gòkè lọ láti ibí yìí Nígbà náà, wọ́n rán àwọn ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí Kiriati Jéárímì wí pé, àwọn Fílístínì ti dá àpótí ẹ̀rí Olúwa padà Ẹ sọ̀kalẹ̀ wá, kí ẹ gbé e gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ yín Sámúẹ́lì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Fílístínì Ní Mísípà Nígbà náà àwọn ará Kiriáti-Jéárímù wá, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa Wọ́n gbé e lọ sí ilé Ábínádábù lórí òkè, wọ́n sì ya Élíásérì ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti ṣọ́ àpótí ẹ̀rí Olúwa Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí Olúwa fi wà ní Kiriati Jéárímù Gbogbo ilé Ísírẹ́lì ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùn réré ẹkún sí Olúwa Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo ilé Ísírẹ́lì pé, Tí ẹ bá ń padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín, Ẹ yẹra kúrò lọ́dọ̀ ọlọ́run àjòjì àti Áṣitarótì kí ẹ sì farayín jìn fún Olúwa kí ẹ sì sin òun nìkan ṣoṣo, òun yóò sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Fílístínì Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹra fún Báálì àti Áṣitarótì, wọ́n sì sin Olúwa nìkan ṣoṣo Nígbà náà ni, Sámúẹ́lì wí pé, Ẹ kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ sí Mísípà, èmi yóò bẹ̀bẹ̀ fún un yín lọ́dọ̀ Olúwa Nígbà tí wọ́n sì ti péjọpọ̀ ní Mísípà, wọ́n pọn omi, wọ́n sì dà á sílẹ̀ níwájú Olúwa Ní ọjọ́ náà, wọ́n gba ààwẹ̀, wọ́n sì jẹ́wọ́ pé, Àwa ti ṣẹ̀ sí Olúwa Sámúẹ́lì sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Mísípà Nígbà tí àwọn Fílístínì gbọ́ pé àwọn Ísírẹ́lì ti péjọ ní Mísípà, àwọn aláṣẹ Fílístínì gòkè wá láti kọlù wọ́n Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ èyí, Ẹ̀rù bà wọ́n nítorí àwọn Fílístínì Wọ́n sọ fún Sámúẹ́lì pé, Má ṣe dákẹ́ kíké pe Olúwa Ọlọ́run wa fún wa, ké pè é kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú ọ̀dọ́ àgùntàn tí ó jẹ́ ọmọ ọmú, ó sì fi rú ẹbọ sísun sí Olúwa Ó sí kè pe Olúwa nítorí ilé Ísírẹ́lì, Olúwa sì dá a lóhùn Nígbà tí Sámúẹ́lì ń ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun, àwọn Fílístínì súnmọ́ tòsí láti bá Ísírẹ́lì ja ogun Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà, Olúwa sán àrá ńlá lu àwọn Fílístínì, ó sì mú jìnnìjìnnì bá wọn, a sì lé wọn níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tú jáde láti Mísípà Wọ́n sì ń lépa àwọn Fílístínì, wọ́n sì pa wọ́n ní àpá rìn títí dé abẹ́ Bẹti-Káírì Sámúẹ́lì mú òkúta kan ó sì fi lé lẹ̀ láàárin Mísípà àti Ṣénì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ẹbẹnésérì, wí pé, Ibí ni Olúwa ràn wá lọ́wọ́ dé Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣẹ́gun Fílístínì, wọn kò sì wá sí agbégbé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ Ní gbogbo ìgbésí ayé Sámúẹ́lì, ọwọ́ Olúwa lòdì sí àwọn Fílístínì Àwọn ìlú láti Ékírónì dé Gátì tí àwọn Fílístínì ti gbà lọ́wọ́ Ísírẹ́lì ni ó ti gbà padà fún Ísírẹ́lì, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ agbègbè rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìṣàkóso àwọn Fílístínì Ìrẹ́pọ̀ sì wà láàárin Ísírẹ́lì àti àwọn Ámórì Sámúẹ́lì tẹ̀ṣíwájú gẹ́gẹ́ bí adájọ́ lórí Ísírẹ́lì Ní ọjọ́ ayé e rẹ̀ Láti ọdún dé ọdún, ó lọ yíká láti Bẹ́tẹ́lì dé Gílígálì dé Mísípà, ó sì ń ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní gbogbo ibi wọ̀nyí Ṣùgbọ́n ó máa ń padà sí ilé rẹ̀ ní Rámà, níbí, ó sì tún ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì níbẹ̀, ó sì kọ́ pẹpẹ kan ṣíbẹ̀ fún Olúwa Ísírẹ́lì Béèrè Fún Ọba Nígbà tí Sámúẹ́lì di arúgbó, ó yan àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ fún Ísírẹ́lì Orúkọ àkọ́bí rẹ̀ a máa jẹ́ Jóẹ́lì àti orúkọ ẹ̀kejì a máa jẹ́ Ábíjà, wọ́n ṣe ìdájọ́ ní Bíáṣébà Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀, kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀ Wọ́n yípadà sí èrè àìṣòótọ́, wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn àgbààgbà ti Ísírẹ́lì péjọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì ní Rámà Wọ́n wí fún un pé, Ìwọ ti di arúgbó, àwọn ọmọ rẹ kò sì rìn ní ọ̀nà rẹ Nísinsìn yìí, yan ọba fún wa kí or lè máa darí wa gẹ́gẹ́ bí i tí gbogbo orílẹ̀ èdè Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n wí pé, Fún wa ní ọba tí yóò darí wa Èyí kò tẹ́ Sámúẹ́lì lọ́rùn, ó sì gbàdúrà sí Olúwa Olúwa sì sọ fún un pé Tẹ́tí sí gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ fún ọ kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n Èmi ni wọ́n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba wọn Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde wá láti Éjíbítì títí di ọjọ́ òní, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ń sin Ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ Nísinsìn yìí, gbọ́ ti wọn ṣùgbọ́n kìlọ̀ fún wọn dáadáa, kí o sì jẹ kí wọ́n mọ irú ohun tí ọba tí yóò jẹ́ lórí wọn yóò ṣe Sámúẹ́lì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa sí àwọn ọmọ ènìyàn tí ó ń béèrè fún ọba lọ́wọ́ rẹ̀ Ó wí pé, Èyí ni ohun tí ọba tí yóò jẹ lórí yín yóò ṣe Yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín, yóò sì mú wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti fún ẹlẹ́sin rẹ, wọn yóò sì máa sáré níwájú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ Yóò yan díẹ̀ láti jẹ́ olórí ẹgbẹ̀rún àti olórí àádọ́ta àti àwọn mìíràn Yóò yan wọ́n láti máa tulẹ̀ oko rẹ̀ àti láti máa kórè rẹ̀ àti àwọn mìíràn láti máa ṣe ohun èlò ogun àti ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ Yóò mú àwọn ọmọbìnrin yín láti máa ṣe olùṣe ìkunra olóòórùn dídùn àti láti máa ṣe àṣè àti láti máa ṣe àkàrà Yóò mú èyí tí ó dára jù nínú oko yín, àti nínú ọgbà àjàrà yín àti nínú igi ólífì yín, yóò sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ Yóò mú ìdásímẹ́wàá hóró ọkà yín àti àká èso àjàrà yín, yóò sì fi fún àwọn oníṣẹ́ àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ Àwọn ìránṣẹ́-kùnrin àti ìránṣẹ́-bìnrin yín àti èyí tí ó dára jù nínú ẹran ọ̀sìn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín ni yóò mú fún ìlò ti ara rẹ̀ Yóò sì mú ìdámẹ́wàá nínú àwọn agbo ẹran yín, yóò sì máa se ẹrú u rẹ̀ Tí ọjọ́ náà bá dé, ẹyin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ọba tí ẹ̀yin ti yàn Olúwa kò sì ní dá a yín lóhùn ní ọjọ́ náà Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kọ̀ láti tẹ́tí sí Sámúẹ́lì wọ́n wí pé, RÁRÁ! A bí ìwọ fẹ́ jẹ́ọba lórí i wa Nígbà náà àwa yóò dàbí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, pẹ̀lú ọba láti darí i wa àti láti jáde lọ níwájú wa láti ja ogun wa Nígbà tí Sámúẹ́lì gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn sọ, ó tún tún un sọ níwájú Olúwa Olúwa dáhùn pé, Tẹ́tí sí wọn, kí o sì yan ọba fún wọn Nígbà náà, Sámúẹ́lì sọ fún àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé, Kí olúkúlùkù padà sí ìlú u rẹ̀ Sámúẹ́lì Fi Òróró Yan Ṣọ́ọ̀lù Ará Bẹ́ńjámínì kan wà, ẹni tí ó jẹ́ aláàánú ọlọ́rọ̀, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kíṣì, ọmọ Ábíélì, ọmọ Sésórì, ọmọ Békórátì, ọmọ Áfíà ti Bẹ́ńjámínì Ó ní ọmọkùnrin kan tí à ń pè ní Ṣọ́ọ̀lù, ọ̀dọ̀mọkùnrin tí ó yanjú, tí ó jẹ́ arẹwà, tí kò sí ẹni tó ní ẹwà jù ú lọ láàárin gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì—láti èjìka rẹ̀ lọ sí òkè, ó ga jú gbogbo àwọn ènìyàn tó kù lọ Nísinsìn yìí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó jẹ́ ti Kíṣì baba Ṣọ́ọ̀lù sì sọnù Nígbà náà, Kíṣì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù ọmọ rẹ̀ pé, Mú ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ pẹ̀lú rẹ kí ẹ lọ láti wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà Bẹ́ẹ̀ ní ó kọjá láàrin àwọn ìlú olókè Éfúráímù, ó sì kọja ní àyíká ilẹ̀ Sálísà, ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn Wọ́n sì kọjá lọ sí òpópó Sálímù, ṣùgbọ́n àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kò sí níbẹ̀ Nígbà náà, ó kọjá ní agbègbè Bẹ́ńjámínì, wọn kò sì rí wọn Nígbà tí wọ́n dé agbégbé Ṣúfù, Ṣọ́ọ̀lù sọ fún ìránṣẹ́ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, Wá, jẹ́ kí á padà sẹ́yìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi yóò dá ìrònú rẹ̀ dúró nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yóò sì bẹ̀rẹ̀ àníyàn nípa wa Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ náà fún un ní èsì pé, Wò ó, ní inú ìlú yìí ọkùnrin ènìyàn Ọlọ́run kan wà ó jẹ́ ẹni tí wọ́n ń bu ọlá fún, àti gbogbo ohun tí ó bá sọ ní ó máa ń jẹ́ òtítọ́ Jẹ́ kí á lọ ṣíbẹ̀ nísinsin yìí, bóyá yóò sọ fún wá ọ̀nà tí a ó ò gbà Ṣọ́ọ̀lù sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, Tí àwa bá lọ, kín ni àwa lè fún ọkùnrin náà Oúnjẹ inú àpò wa ti tán A kò sì ní ẹ̀bùn láti mú lọ sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run Kí ni a ní Ìránṣẹ́ sì dá a lóhùn lẹ́ẹ̀kan sí i Wò ó, ó wí pé, Mo ní ìdámẹ́rin Ṣékélì fàdákà lọ́wọ́ Èmi yóò fún ènìyàn Ọlọ́run náà kí ó lè fi ọ̀nà hàn wá Ṣọ́ọ̀lù sọ fún ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ pé ó dára Jẹ́ kí a lọ Wọ́n jáde lọ sí ìlú tí ènìyàn Ọlọ́run náà ń gbé Bí wọ́n ṣe ń lọ ní orí òkè sí ìlú náà, wọ́n pàdé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó ń jáde í bọ̀ láti wá pọn omí Wọ́n sì bi wọ́n, Ṣé wòlíì náà wà níbí Ó wà, wọ́n dáhùn Ó ń bẹ níwájú u yín, múra nísinsìn yìí, ó ṣẹ̀ ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lónìí ni, nítorí àwọn ènìyàn ní ẹbọ rírú ni ibi gíga Kété tí ẹ bá ti wọ ìlú, ẹ ó rí i kí ó tó lọ sí ibi gíga láti lọ jẹun Àwọn ènìyàn kò sì ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóò fi dé Torí ó gbúdọ̀ bùkún ẹbọ náà lẹ́yìn náà, àwọn tí a pè yóò jẹun Gòkè lọ nísinsìn yìí ó yẹ kí ẹ rí i ní àkókò yìí Wọ́n gòkè lọ sí ìlú náà, bí wọ́n ti ń wọlé, níbẹ̀ ni Sámúẹ́lì, ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn bí ó ti ń lọ ibi gíga náà Olúwa ti sọ létí Sámúẹ́lì ní ijọ́ kan kí Ṣọ́ọ̀lù ó tó dé pé, Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Fílístínì Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi Nígbà tí Sámúẹ́lì fojú rí Ṣọ́ọ̀lù, Olúwa sọ fún un pé, Èyí ni ọkùnrin tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀, yóò darí àwọn ènìyàn mi Ṣọ́ọ̀lù sì súnmọ́ Sámúẹ́lì ní ẹnu ọ̀nà ìlú, ó sì wí pé, Sọ fún mi èmi ń bẹ̀ ọ́ níbo ni ilé wòlíì náà wà Sámúẹ́lì dáhùn pé, Èmi ni wòlíì náà Ẹ máa gòkè lọ ṣáájú mi, ní ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí Ní òwúrọ̀ ni èmi yóò tó jẹ́ kí ẹ lọ, gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ ní èmi yóò sọ fún ọ Fún ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sọnù fún ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn, má ṣe dàamú nípa wọ́n a ti rí wọn Sí ta ni gbogbo ìfẹ́ Ísírẹ́lì wà Bí kì í ṣe sí ìwọ àti sí gbogbo ilé baba à rẹ Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, Ṣùgbọ́n èmi kì í há à ṣe ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì Kékeré nínú ẹ̀yá Ísírẹ́lì Ìdílé mi kò há rẹ̀yìn jùlọ nínú gbogbo ẹyà Bẹ́ńjámínì Èésì ti ṣe tí ìwọ sọ̀rọ̀ yìí sí mi Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú Ṣọ́ọ̀lù pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ inú gbọ̀ngàn, ó sì mú wọn jókòó sí iwájú àwọn tí a pè—tí wọn tó ọgbọ̀n Sámúẹ́lì sọ fún aláṣè pé, Mú ìpín ẹran tí mo fún ọ wá, èyí tí mo sọ fún ọ pé kí o yà sọ́tọ̀ Alásè náà sì gbé ẹṣẹ̀ náà pẹ̀lú ohun tí ó wà lórí i rẹ̀, ó sì gbé e ṣíwájú Ṣọ́ọ̀lù Sámúẹ́lì wí pé, Èyí ni ohun tí a fi pamọ́ fún ọ Jẹ, nítorí a yà á sọ́tọ̀ fún ọ, fún ìdí yìí, láti ìgbà tí mo ti wí pé, Mo ní àlejò tí a pè   Ṣọ́ọ̀lù sì jẹun pẹ̀lú Sámúẹ́lì ní ọjọ́ náà Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti sọ̀kalẹ̀ láti ibí gíga náà wá sí inú ìlú, Sámúẹ́lì sì bá Ṣọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ lórí òrùlé ilé e rẹ̀ Wọ́n sì dìde ní àfẹ̀mọ́jú, ó pe Ṣọ́ọ̀lù sórí òrùlé pé, Múra, èmi yóò rán ọ lọ Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù múra tán òun àti Sámúẹ́lì jọ jáde lọ síta Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìpẹ̀kun ìlú náà, Sámúẹ́lì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Sọ fún ìránṣẹ́ náà kí ó máa lọ ṣáájú u wa, ìránṣẹ́ náà sì ṣe bẹ̀ẹ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó dúró díẹ̀, kí èmi kí ó lè sọ ọrọ̀ láti ọ̀dọ Ọlọ́run fún ọ Ọpẹ́ Fún Ìgbàgbọ́ Àwọn Ará Tẹsalóníkà Pọ́ọ̀lù, Sílásì àti Tímótíù A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalóníkà, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jésù Kírísítì Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jésù Kírísítì kí ó jẹ́ tiyín Gbogbo ìgbà ni a máa ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí yín, a sì ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo pẹ̀lú A ń rántí lí àìsinmi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Bàbá iṣẹ́ ìgbàgbọ́yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró sinsin ìretí yín nínú Jésù Kírísítì Olúwa wa Àwa mọ̀ dájúdájú, ẹ̀yin olùfẹ́ wa, wí pé Ọlọ́run ti yàn yín fẹ́ fún ara rẹ̀ Nítorí pé, nígbà tí a mú ìyìn rere tọ̀ yín wà, kò rí bí ọ̀rọ̀ lásán tí kò ní ìtumọ̀ sí i yín, bí kò ṣe pẹ̀lú agbára, pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, pẹ̀lú ìdánilójú tó jinlẹ̀ Bí ẹ̀yin ti mọ irú ènìyàn tí àwa jẹ́ láàrin yín nítorí yín Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mi Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá fi di àpẹrẹ fún gbogbo àwọn Kírísírẹ́nì tó wà ní agbégbé Makedóníà àti Ákáyà Ọ̀rọ̀ Olúwa ti gbilẹ̀ níbi gbogbo láti ọ̀dọ̀ yín láti agbégbé Makedóníà àti Ákáyà lọ, ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run tàn káàkiri Nítorí náà, a kò ni láti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wọn nípa rẹ̀ Ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i ròyìn fún wa bí ẹ ti gbà wá lálejò Wọ́n ròyìn fún wa pẹ̀lú pé, ẹ ti yípadà kúrò nínú ìbọ̀rìṣà àti wí pé Ọlọ́run alààyè nìkan ṣoṣo ni ẹ ń sìn àti láti fi ojú sọ́nà fún ìpadàbọ̀ Ọmọ Ọlọ́run ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú, Jésù, ẹni tí ó gbà wá lọ́wọ́ ìbínú tí ń bọ̀ Iṣẹ́ Pọ́ọ̀lù Ní Ìjọ Tẹsalóníkà Ẹ̀yin pàápàá mọ̀, ará, pé ìbẹ̀wò wa sí i yín kì í ṣe ní asán Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Fílípì bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìyìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í se ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìyìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í se bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò se Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa A kò bèèrè ìyìn lọ́dọ̀ yín tàbí fún ara wa Gẹ́gẹ́ bí àpósítélì Kírísítì a ò bá ti di àjàgà fún un yín Ṣùgbọ́n àwa se pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láàrin yín tí a sì se ìtọ́jú yín gẹ́gẹ́ bí ìyá ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀ A fẹ́ràn yín púpọ̀, èyí ló mu kí ó ṣe é ṣe fún wa láti pín ìyìnrere náà fún yín pẹ̀lú ìgbésí ayé àwa pàápàá Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa lọ́sàn-án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnìkẹ́ni bí a ti ń wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrin ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́ Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ bí àwa tí ń ba olúkúlùkù yín lò gẹ́gẹ́ bí baba ti ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ ìyànjú, ìtùnnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkararẹ̀ Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́ Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́se àwọn ìjọ tí o wà ní Jùdíà jẹ Bí a ti gbógun tì wọ́n, láti ọwọ́ àwọn ará ìlú wọn , bẹ́ẹ̀ ni a gbógun ti ẹ̀yin pàápàá láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù, àwọn tí wọ́n pa Jésù Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìyìnrere dúró láàrin àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà Ẹ̀sẹ̀ wọn ń di púpọ̀ síi lójoojúmọ́ Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn Ẹ̀yin ará olùfẹ́, lẹ́yìn ìgbà tí a ti kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀ , pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtara ni àwa ṣe àníyàn tí a sì fẹ́ gidigidi láti fi rí i yín Nítorí àwa fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ yín—àní èmi, Pọ́ọ̀lù, gbìyànjú ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti wá, ṣùgbọ́n Èṣù ú dè wá lọ́nà Kí ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, tàbí adé wa nínú èyí tí a ó sògo níwájú Jésù Olúwa nígbà tí òun bá dé Ṣé ẹ̀yin kọ ní Nítòótọ́, ẹ̀yin ni ògo àti ayọ̀ wa Tímótíù Nítorí ìdí èyí, nígbà tí ara mi kò gbà á mọ́, mo pinnu láti nìkan dúró ní ìlú Átẹ́nì Mo sì rán Tímótíù, arákùnrin àti alábáṣiṣẹ́ pọ̀ wá, láti bẹ̀ yín wò Mo rán an láti fún ìgbàgbọ́ yín lágbára àti láti mú yín lọ́kà le àti kí ó má sì ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, nínú ìṣòro tí ẹ ń là kọjá Láìsí àníàní, ẹ mọ̀ gbangba pé, irú ìṣòro báwọ̀nyí wà nínú ètò Ọlọ́run fún àwa Kírísítẹ́nì Tó bẹ́ẹ̀ tí a fi kìlọ̀ fún yín pé ìjìyà inúnibíni yóò de Ó sì rí bẹ́ẹ̀ nítòótọ́ Bí mo wí tẹ́lẹ̀, nígbà tí ara mi kò gba ìdákẹ́jẹ́ẹ́ náà, mo rán Tímótíù láti bẹ̀ yín wò, kí ó lè mọ̀ bóyá ìgbàgbọ́ yín sì dúró gbọn-ingbọn-in Mo funra sí i wí pé, sàtánì ti ṣẹ́gun yín Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ wa jásí aṣán Nísìnsinyìí, Tímótíù ti dé pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀ wí pé, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín sì lágbára bí i ti àtẹ̀yìnwá Inú wa dùn láti gbọ́ wí pé ẹ sì ń rántí ìbágbé wa láàrin yín pẹ̀lú ayọ̀ Tímótíù tún fi yé wa pé bí ó ti mú wa lọ́kàn tó láti rí i yín, ni ó ṣe ẹ̀yin pàápàá Nítorí náà, ẹ̀yin ará, inú wá dùn jọjọ nínú gbogbo ìyọnu àti ìjìyà wa níbí nítorí pé àwa mọ̀ nísinsinyìí pé, ẹ̀yin sì dúró gbọn-ingbọn-in fún Olúwa Kò sí nǹkan tí a kò lè fi ara dà níwọ̀n ìgbà tí a ti mọ̀ pé, ẹ̀yin sì dúró gbọn-ingbọn-in fún Olúwa Kò ṣé é ṣe fún wa láti dá ọpẹ́ tán lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ó máa ń kún ọkàn wa nípa àdúrà wa fún un yín Nítorí pé àwa ń gbàdúrà fún un yín lọ̀sán-án àti lóru Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti se àtúnṣe ibi tí ìgbàgbọ́ yín bá kù sí À ń gbàdúrà wí pé, kí ó wu Ọlọ́run pàápàá àti Olúwa wa Jésù Kírísítì láti rán wa padà sí ọ̀dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kan sí í A sì béérè pé, kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ yín yóò fi gbòòrò tí yóò sì ṣàn kan olúkúlùkù yín Èyí yóò jẹ́ àpẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwa náà se sàn kan ẹ̀yin náà Nípa èyí, ọkàn yín yóò di alágbára, àìlẹ́sẹ̀ àti Mímọ́ nípa Ọlọ́run, Baba wa Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jésù Kírísítì yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀ Gbígbé Ìgbé-Ayé Tó Wu Ọlọ́run Ní ìparí, ará, a sọ fún un yín bí ẹ ti ń gbé láti wu Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí ń ṣe Nísinsìnyìí, a bèèrè, a sì ń rọ̀ yín nínú Jésù Olúwa láti ṣe bẹ́ẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ sí Nítorí pé, ẹyin mọ àṣẹ tí a pa fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa Jésù Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ẹ jẹ́ mímọ, kí ẹ sì yàgò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbérè, kí ẹnikọ̀ọ̀kan yín kọ́ láti sàkóso ara rẹ̀ ní ọ̀nà mímọ́ àti pẹ̀lú ọlá, kì í ṣe ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà, ẹni tí kò mọ Ọlọ́run àti pé nínú ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹnikẹ́ni yín máa ṣe kùnà arákùnrin rẹ̀ nípa ohunkóhun Olúwa yóò jẹ àwọn ènìyàn níyà fún gbogbo ẹ̀sẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti ń sọ fún un yín tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ Nítorí Ọlọ́run kò pè wá sínú àìmọ́, bí kò ṣe sínúìgbé-ayé mímọ́ Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó kọ òfin yìí, kì í se òfin ènìyàn ni ẹni náà kọ̀, bí kò ṣe òfin Ọlọ́run ẹni tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún ni Ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ará a ò ní láti tún kọ̀wé sí i yín, ìdí ni pé, Ọlọ́run pàápàá ń kọ́ yín láti fẹ́ràn ara yín Nitòótọ́, ẹ ní ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin tí ó wà káàkiri Makidóníà Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ àwa ń bẹ̀ yín, ará, pé kí ẹ̀yin kí ó máa tẹ̀síwájú nínú rẹ̀ Ẹ jẹ́ kí èyí jẹ́ ìfẹ́ ọkàn yín láti gbé jẹ́ẹ́ àti láti mọ ti ara yín àti kí olúkúlùkù kọjú sí iṣẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti wí fún yín Èyí yóò mú kí àwọn tí kì í se Kírísítẹ́nì gbẹ́kẹ̀lé yín àti láti bu ọlá fún yín pẹ̀lú Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò ní máa wo ojú ẹnikẹ́ni láti fún yín ni owó tí ẹ ó fi san gbèṣè Ẹ̀yin ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó jẹ́ òpè ní ti àwọn tí ó ti sùn, pé kí ẹ máa banújẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn yóòkù tí kò ní ìrètí A gbàgbọ́ pé, Jésù kú, ó sì tún jíǹde, pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo àwọn tí ó ti sùn nínú rẹ̀ padà wá Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, pé àwa tí ó wà láàyè, tí a sì kù lẹ́yìn de àtiwá Olúwa, bí ó ti wù kí ó rí, kì yóò ṣáájú àwọn tí ó sùn láti pàdé rẹ̀ Nítorí pé, Olúwa fúnraarẹ́ yóò sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, pẹ̀lú ariwo àṣẹ ńlá àti ohùn àwọn ańgẹ́lì ti àwọn ańgẹ́lì ti àwọn ti ìpè Ọlọ́run, àwọn òkú nínú Kírísítì yóò sì kọ́kọ́ jíǹde Nígbà náà ni a ó gba àwa tí ó sì wà láàyè sókè nínú àwọ̀sánmọ̀ láti ọwọ́ Olúwa A ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀ títí láéláé Nítorí náà, ẹ tu ara yín nínú, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Nísinsìnyìí, ará, a kò nílò láti kọ ìwé sí i yín mọ́ nípa àkókò àti ìgbà, nítorí ẹ̀yin pàápàá mọ̀ wí pé ọjọ́ Olúwa yóò wàá bí olè lóru Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, Àláfíà àti àbò, nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí rí ibi ààbò láti sá sí Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ará, kò sí nínú òkùnkùn nípa nǹkan wọ̀nyí tí ọjọ́ Olúwa yóò fi dé bá yín bí olè Nítorí gbogbo yín ni ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán gangan Ẹ kì í ṣe tí òru tàbí tí òkùnkùn mọ́ Nítorí náà, ẹ kíyèsára yín kí ẹ má ṣe sùn bí àwọn ẹlòmíràn Ẹ máa sọ́nà kí ẹ sì máa pa ara yín mọ́ Nítorí àwọn tí owọ́n ń sùn, a máa sùn ní òru, àwọn ẹni tí ń mu àmupara, a máa mú un ní òru Ṣùgbọ́ń àwa jẹ́ ti ìmọ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí a pa ara wa mọ́, ní gbígbé ìgbàgbọ́ wọ̀ àti ìfẹ́ bí awo igbaaya ni òru àti ìrètí ìgbàlà bí asìborí Nítorí pé, Ọlọ́run kò yàn wa láti da ìbínú rẹ̀ gbígbóná sí orí wa, ṣùgbọ́n ó yàn láti gbà wá là nípasẹ̀ Olúwa wa, Jésù Kírísítì Jésù kú fún wa kí a lè ba à gbé títí láéláé Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ yálà a sùn tàbí a wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀ Nítorí náà, ẹ máa gba ara yín níyànjú, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe Ẹ̀yin ará, ẹ fi ọlá fún àwọn olórí tí ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láàrin yín tí wọn ń kìlọ̀ fún jẹ́ olórí fún yín nínú Olúwa Ẹ bu ọlá fún wọn gidigidi nínú ìfẹ́, nítorí iṣẹ́ wọn Ẹ sì máa wà ni àlàáfíà láàrin ara yín Ẹ̀yin ará mi, ẹ kìlọ̀ fún àwọn ọ̀lẹ ti ó wà láàrin yín, ẹ gba àwọn tí ẹ̀rù ń bà ní ìyànjú, ẹ tọ́jú àwọn aláìlera pẹ̀lẹ̀pẹ̀lẹ́, kí ẹ sì ní sùúrù pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ maa lépa èyí tíi ṣe rere láàrin ara yín àti sí ènìyàn gbogbo Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo ipòkípò tí o wù kí ẹ wà nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kírísítì Jésù nítòótọ́ Ẹ má ṣe pa iná Ẹ̀mí Mímọ́ Ẹ má ṣe kẹ́gàn àwọn ti ń ìsọtẹ́lẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹ dán gbogbo nǹkan wò Ẹ di èyí tí ṣe òtítọ́ mú Ẹ yẹra fún ohunkóhun tí í ṣe ibi Kí Ọlọ́run àlàáfíà pàápàá wẹ̀ yín mọ́, kí ó sì yà yín sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀ Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́, títí di ìgbà wíwá Jésù Kírísítì Olúwa wa Olótítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe Ẹ̀yin ará, ẹ gbàdúrà fún wa Ẹ gbà ara yín ní ọwọ́ ní orúkọ mi pẹ̀lú ọkàn funfun Mo pàṣẹ fún yín níwájú Olúwa pé, kí ẹ ka lẹ́ta yìí fún gbogbo àwọn ará Ki oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, wà pẹ̀lú yín Àmín Ìkìlọ̀ Lòdì Sí Olùkọ́ni Èké Ti Òfin Pọ́ọ̀lù, àpósítélì Kírísítì Jésù gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa, àti Jésù Kírísítì ìrètí wa Sí Tímótíù ọmọ mi nínú ìgbàgbọ́ Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jésù Kírísítì Olúwa wa Bí mo se rọ̀yín nígbàtí mò ń lọ sí Makedóníà, ẹ dúró ní Éfésù, kí ẹ lè dá àwọn ènìyàn kan lẹ́kun láti má ṣe kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ èké mọ́ kí wọ́n má sì ṣe fiyèsí àwọn ìtàn-asán, àti ìtàn-ìran aláìlópin Irú èyí máa ń mú iyàn jíjà wá dípò iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run èyí tí í ṣe ti ìgbàgbọ́ Ète àṣẹ náà ni ìfẹ́ ti ń jáde wá láti inú ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn rere àti ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn Àwọn ẹlòmíràn ti yapa kúrò tí wọ́n sì yà sápákan sí ọ̀rọ̀ asán Wọ́n ń fẹ́ ṣe olùkọ́ òfin òye ohun tí wọ́n ń wí kò yé wọn tàbí ti ohun tí wọ́n ń fi ìgboyà tẹnumọ́ Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá àti àwọn apànìyàn, fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro Gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere ti ògo Ọlọ́run olùbùkún, tí a fi sí ìtọ́jú mi Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹni tí ó fún mi ní agbára, àní Kírísítì Jésù Olúwa wa, nítorí tí ó kà mí sí olóòótọ́ ní yíyànmí sí iṣẹ́ rẹ̀ Bí mo tilẹ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run rí, àti onínúnibíni àti ìkà ènìyàn ṣùgbọ́n mo rí àánú gbà, nítorí tí mo ṣe é nínú àìmọ̀ àti àìgbàgbọ́ Oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa sì pọ̀ rékọjá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà, pé Jésù Kírísítì wá sí ayé láti gba ẹlẹ́sẹ̀ là nínú àwọn ẹni tí èmi jẹ́ búburú jùlọ Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe rí àánú gbà, pé lára mi, bí olórí ẹlẹ́sẹ̀ ni kí Jésù Kírísítì fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn bí àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò gbà á gbọ́ sí ìyè àìnípẹ̀kun ìkẹyìn Ǹjẹ́ fún Ọba ayérayé, àìdíbàjẹ́, àìrí, Ọlọ́run kan ṣoṣo, ni ọlá àti ògo wà fún láéláé Àmín Àṣẹ yìí ni mo pa fún ọ, Tímótíù ọmọ mi, gẹ́gẹ́ bí ìsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí tó ó ti ṣáájú nípa rẹ̀, pé nípaṣẹ̀ wọ́n kí ìwọ lè máa ja ìjà rere Máa ní ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn rere Àwọn ẹlòmíràn tanù lọ́dọ̀ wọn tí wọ́n sì rí ọkàn ìgbàgbọ́ wọn Nínú àwọn ẹni tí Híménéù àti Alẹkisáńdérù wà àwọn tí mo ti fi lé Sàtánì lọ́wọ́, kí a lè kọ́ wọn kí wọn má sọ̀rọ̀-òdì mọ́ Àwọn Ẹ̀kọ́ Lórí Ìsìn Nítorí náà mo gbà yín níyànjú ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa bẹ̀bẹ̀, kí a máa gbàdúrà, kí a máa sìpẹ̀, àti kí a máa dúpẹ́ nítorí gbogbo ènìyàn Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àláfíà àti ìdákẹ́jẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́ Nítorí èyí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Olúgbàlà wa Ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́ Nítorí Ọlọ́run kan ní ń bẹ, onílàjà kan pẹ̀lú láàrin Ọlọ́run àti ènìyàn, àní Kírísítì Jésù ọkùnrin náà Ẹni ti ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn—ẹ̀rí tí a fi fún ni ní àkókò tó yẹ Nítorí èyí tí a yàn mi ṣe oníwàásù, Àpósítélì—òtítọ́ ni èmi ń sọ, èmi kò ṣèké olùkọ́ àwọn aláìkọlà nínú ìgbàgbọ́ àti òtítọ́ Mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà níbi gbogbo, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́ sókè, ní àìbínú àti àìjiyàn Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsí ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá kì í ṣe pẹ̀lú irun-dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye, Bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run Jẹ́ kí obìnrin máa fi ìdákẹ́jẹ́ àti ìtẹríba gbogbo kọ́ ẹ̀kọ́ Ṣùgbọ́n èmi kò fi àṣẹ fún obìnrin láti máa kọ́ni, tàbí láti pàṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe kí ó dákẹ́jẹ́ Nítorí Ádámù ni a kọ́ dá, lẹ́yìn náà, Éfà Ádámù kọ́ ni a tàn jẹ, ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn tí ó sì di ẹlẹ́ṣẹ̀ Ṣùgbọ́n a ó gbà àwọn obìnrin là nípa ìbímọ wọn, bí wọ́n bá dúró nínú ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti ìwà-mímọ́ pẹ̀lú ìwà àìrékọjá Alábójútó Àti Díákónì Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, bí ẹnìkan bá fẹ́ ipò Bíṣọ́ọ̀bù, iṣẹ́ rere ni ó ń fẹ́, Ǹjẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùsọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà yíyẹ, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́ Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí alu-ni, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó Ẹni tí ó káwọ́ ilé ara rẹ̀ gírígírí, tí ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹríba pẹ̀lú ìwà àgbà gbogbo Ṣùgbọ́n bí ènìyàn kò bá mọ̀ bí a ti ń ṣe ìkáwọ́ ilé ara rẹ̀, òun ó há ti ṣe lè tọ́jú ìjọ Ọlọ́run Kí ó má jẹ́ ẹni titun ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́, kí ó má baà gbéraga, a sì ṣubú sínú ẹ̀bi Èsù Ó sì yẹ kí ó ni ẹ̀rí rere pẹ̀lú lọ́dọ̀ àwọn tí ń bẹ lóde kí ó má baà bọ́ sínú ẹ̀gàn àti sínú ìdẹ́kun Èṣù Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn Díákónì láti ní ìwà àgbà, kí wọ́n máa jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n máa fi ara wọn fún wáìnì púpọ̀, kí wọ́n má jẹ́ olójúkòkòrò Kí wọn máa di ohun ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ọkàn funfun Kí a kọ́kọ̀ wádìí àwọn wọ̀nyí dájú pẹ̀lú nígbà náà ni kí a jẹ́ kí wọn ó ṣiṣẹ́ díákónì, bí wọn bá jẹ́ aláìlẹ́gàn Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn obìnrin láti ni ìwá àgbà, kí wọn má jẹ́ asọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn bí kò ṣe aláìrékọjá, olóòótọ́ ní ohun gbogbo Kí àwọn díákónì jẹ́ ọkọ obìnrin kan, kí wọn káwọ́ àwọn ọmọ àti ilé ara wọn dáradára Nítorí àwọn tí ó lo ipò díákónì dáradára ra ipò rere fún ara wọn, àti ìgboyà púpọ̀ nínú ìgbàgbọ́ tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù Ìwé nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ sí ọ, mo sì ń réti àti tọ̀ ọ́ wá ní lọ́ọ́lọ́ọ́ Ṣùgbọ́n bí mo bá pẹ́, kí ìwọ lè mọ̀ bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn láti máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run, tì í ṣe ìjọ Ọlọ́run, alààyè, ọ̀wọ́n àti ìpìlẹ̀ òtítọ́ Láìṣiyè méjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run ẹni tí a fi hàn nínú ara, tí a dáláre nínú Ẹ̀mí, ti àwọn ańgẹ́lì rí, tí a wàásù rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, tí a gbàgbọ́ nínú ayé, tí a sì gbà sókè sínú ògo Àwọn Ẹ̀kọ́ Sí Tímótíù NÍṢÍNṢIN YÌÍ, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èsù Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkarawọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó Àwọn tí ń dá-ni-lẹ́kun láti gbéyàwó ti wọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́ Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà á sí mímọ́ Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ iránṣẹ́ rere ti Kírísítì Jésù, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwá-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti igbé-ayé ìṣinṣinyìí àti ti èyí tí ń bọ̀, Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ̀wọ́gbà gbogbo Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwá ní ìrèti nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́ Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ̀ kí ó máa kọ́ni Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan èrè rẹ ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwàhíhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́, Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbani-níyànjú àti ìkọ́ni Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà Má a fiyèsí nǹkan wọ̀nyí fi ara rẹ fún wọn pátápátá kí ìlọṣíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn Má a ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ máa dúró láiyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là Ìmọ̀ràn Nipa Àwọn Opó, Àwọn Alagbà Àti Àwọn Ẹrú Má ṣe bá àgbàlagbà ọkùnrin wí, ṣùgbọ́n kí ó máa gbà á níyànjú bíi bàbá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bí arákùnrin Àwọn àgbàlagbà obìnrin bí ìyá àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bí arábìnrin nínú ìwà mímọ́ Bọ̀wọ̀ fún àwọn opó ti í ṣe opó nítòótọ́ Ṣùgbọ́n bí opó kan bá ni ọmọ tàbí ọmọ-ọmọ, jẹ́ kí wọn kọ́kọ́ kọ́ bí a ti ń ṣe ìtọ́jú ilé àwọn tìkárawọn, kí wọn sì san oore àwọn òbí wọn padà nítorí pé èyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Ǹjẹ́ ẹni ti í ṣe opó nítòótọ́, ti ó ṣe òun nìkan, a máa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a sì máa dúró nínú ẹ̀bẹ̀ àti nínú àdúrà lọ́sàn àti lóru Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi ara rẹ fún ayé-jíjẹ, ó kú nígbà tí ó wà láàyè Nǹkan wọ̀nyí ni kí wọn máa paláṣẹ, kí wọn lè wà láìlẹ́gàn Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ara ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ Kọ orúkọ ẹni tí kò bá dín ni ọgọ́ta ọdún sílẹ̀ bí opó, lẹ́yìn ti ó ti jẹ́ aya ọkọ kan Ẹni ti a jẹ́rì rẹ̀ fún iṣẹ́ rere bí ẹni ti ó ti tọ́ ọmọ dàgbà, ti ó ń ṣe ìtọ́jú àlejò, tí ó sì ń wẹ ẹṣẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, tí ó ti ran àwọn olupọ́njú lọ́wọ́, tí ó sì ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo Ṣùgbọ́n kọ̀ àwọn opó tí kò dàgbà nítorí pé nígbà ti wọn bá ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Kírísítì, wọn á tún fẹ́ láti gbéyàwó Wọn á di ẹlẹ́bi, nítorí tí wọn ti kọ ìgbàgbọ́ wọn ìṣáájú sílẹ̀ Àti pẹ̀lú wọn ń kọ́ láti ṣe ọ̀lẹ, láti máa kiri láti ile-dé-ilé, kì í ṣe ọ̀lẹ nìkan, ṣùgbọ́n onísọkúsọ àti olófòófó pẹ̀lú, wọn a máa sọ ohun tí kò yẹ Nítorí náà, mo fẹ́ kí àwọn opó tí kò dàgbà máa gbéyàwó, kí wọn máa bímọ, kí wọn máa ṣe alábòójútó ilé, kí wọn má ṣe fi àyè sílẹ̀ rárá fún ọ̀tá náà láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn Nítorí àwọn mìíràn ti yípadà kúrò sí ẹ̀yìn Sàtánì Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tí ó gbàgbọ́ bá ní àwọn opó, kí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, kí a má sì di ẹrù lé ìjọ, kí wọn lè máa ran àwọn ti í ṣe opó nítòótọ́ lọ́wọ́ Àwọn alàgbà ti ó ṣe àkóso dáradára ni kí a kà yẹ sí ọlá ìlọ́po méjì, pẹ̀lu pẹ̀lú àwọn ti ó ṣe làálàá ni ọ̀rọ̀ àti ni kíkọ́ni Nítorí tí Ìwé-Mímọ́ wí pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹnu Àti pé, ọ̀yà alágbàse tọ́ sí i Má ṣe gba ẹ̀sùn sí alàgbà kan, bí kò ṣe láti ẹnu ẹlẹ́rìí méjì-mẹ́ta Bá àwọn tí ó ṣẹ̀ wí níwájú gbogbo ènìyàn, kí àwọn ìyókù pẹ̀lú bà á lè bẹ̀rù Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kírísítì Jésù, àti àwọn ańgẹ́lì àyànfẹ́ kí ìwọ máa ṣakíyèsí nǹkan wọ̀nyí, láìṣe ojúṣàájú, láti fi ègbè ṣe ohunkóhun Má ṣe fi ìkánjú gbe ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe jẹ́ alábàápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn pa ara rẹ mọ́ ní ìwà funfun Ma ṣe máa mu omi nìkan, ṣùgbọ́n máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí inú rẹ, àti nítorí àìlera ìgbàkúùgbà Ẹ̀sẹ̀ àwọn ẹlòmíràn a máa hàn gbangba, a máa lọ ṣáájú sí ìdájọ́ tí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú a sì máa tẹ̀lé wọn Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni iṣẹ́ rere wa máa ń hàn gbangba bí wọn kò tilẹ̀ tíì hàn, wọn kò lè farasin títí Àwọn Ẹrú Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí i ṣe ẹrú lábẹ́ ìsìnrú máa ka àwọn olówó tí ó ni wọ́n yẹ sí ọlá gbogbo, kí a má bà á sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ Àwọn ti ó ní ọ̀gá onígbàgbọ́, kí wọn má ṣe ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn nítorí tí wọn jẹ́ arákùnrin ṣùgbọ́n kí wọn túbọ̀ máa sìn wọ́n, nítorí àwọn tí í ṣe alábàápín iṣẹ́ rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfẹ́ Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa kọ́ ni, kí o sì máa fi gbani níyànjú Bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ mìíràn, ti kò sì gba ọ̀rọ̀ ti ó yè kooro, ti Jésù Kírísítì Olúwa wa, àti ẹ̀kọ́ ti ó bá ìwà-bí-Ọlọ́run mu, Ó gbéraga, kò mọ̀ nǹkankan, bí kò ṣe ìyànjú àti ìjà nípa ọ̀rọ̀ èyí tí ó ń mú ìlara, ìjà, ọ̀rọ̀-búburú wá, Àti ọ̀rọ̀ àyípo àwọn ènìyàn ọlọ́kàn èérí ti kò sí òtítọ́ nínú wọn, ti wọn ṣèbí ọ̀nà sí èrè ni ìwà-bí-Ọlọ́run yẹra lọ́dọ̀ irú àwọn wọ̀nyí Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni Nítorí a kò mu ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yóò tẹ́ wa lọ́rùn Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹkùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa-ni-lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn sìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀ Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrú, ìwà tútù Má a ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀ Mo paṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jésù Kírísítì, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọ́ńtíù Pílátù, Kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jésù Kírísítì Èyí ti yóò fi hàn ní ìgbà tirẹ̀, Ẹni tí í ṣe Olùbùkún àti Alágbára kan ṣoṣo náà, Ọba àwọn ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa Ẹnìkan ṣoṣo tí ó ní àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí tí a kò sì lè rí ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀ Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìṣinṣinyìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò se lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ láti lò Kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fúnni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbákẹ́dùn Kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú Tìmótíù, máa sọ ohun tí a fi sí ìtọ́jú rẹ, yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ìjiyàn ohun tí a ń fi èké pè ni ìmọ̀ Èyí tí àwọn ẹlòmíràn jẹ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì sìnà ìgbàgbọ́ Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú rẹ Àmín Sólómónì Béèrè Fún Ọgbọ́n Sólómónì ọmọ Dáfídì fìdí ara rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lórí ìjọba rẹ̀ Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú u rẹ̀, ó sì jẹ́ kí ó ga lọ́pọ̀lọpọ̀ Nígbà náà, Sólómónì bá gbogbo Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ sí àwọn alákóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀rún, sí àwọn adájọ́ àti sí gbogbo àwọn olórí Ísírẹ́lì, àwọn olórí ìdílé Pẹ̀lú Sólómónì, àti gbogbo àpéjọ lọ sí ibi gíga ní Gíbíónì, nítorí àgọ́ Ọlọ́run fún pípàdé wà níbẹ̀, tí Móse ìránṣẹ́ Olúwa ti kọ́ ni ihà Nísinsinyìí, Dáfídì ti gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run wá láti Kiriati-Jéárímù sí ibi tí ó ti pèsè fún un, nítorí ó ti kọ́ àgọ́ fún un ni Jérúsálẹ́mù Ṣùgbọ́n pẹpẹ idẹ tí Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrù, ti ṣe wà ní Gíbíónì níwájú àgọ́ Olúwa Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì àti gbogbo àpèjọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níbẹ̀ Sólómónì gòkè lọ sí ibi pẹpẹ idẹ níwájú Olúwa ní ibi àgọ́ ìpàdé, ó sì rú ẹgbẹ̀run ọrẹ sísun lórí rẹ̀ Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọ́run farahàn Sólómónì, ó sì wí fún un pé, Béèrè fún ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ kí n fún ọ Sólómónì dá Ọlọ́run lóhùn pé, Ìwọ ti fi àánú ńlá han Dáfídì baba à mi ìwọ sì ti fi mí jẹ ọba ní ipò rẹ̀ Nísinsinyìí Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ìlérí rẹ sí baba à mi Dáfídì di mímúsẹ, nítorí ìwọ ti fi mí jẹ ọba lóri àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀ Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀, kí èmi kí ó lè tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ́nà, nítorí ta ni ó le è ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ tí ó pọ̀ yanturu wọ̀nyí Ọlọ́run wí fún Solómónì pé, Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ ọkàn rẹ nìyí, tí ìwọ kò sì béèrè, fún ọrọ̀, ọlá tàbí ọ̀wọ̀, tàbí fún ikú àwọn ọ̀ta rẹ, àti nígbà tí ìwọ kò ti béèrè fún ẹ̀mí gígùn, ṣùgbọ́n tí ìwọ béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti ṣàkóso àwọn ènìyàn mi tí èmi fi ọ́ jẹ ọba lé lórí, Nítorí náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ọrọ̀, ọlá àti ọ̀wọ̀, irú èyí tí ọba ti ó wà ṣáájú rẹ kò ní, tí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ kò sì ní ní irú rẹ̀ Nígbà náà ni Sólómónì sì ti ibi gígá Gíbíónì lọ sí Jérúsálẹ́mù láti iwájú àgọ́ ìpàde Ó sì jọba lórí Ísírẹ́lì Sólómónì kó kẹ̀kẹ́ àti ẹsin jọ, ó sì ní ẹgbàáje kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàafà ẹlẹ́sin, tí ó kó pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Jérúsálẹ́mù ọba náà ṣe fàdákà àti wúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti wọ́pọ̀ ní Jérúsálẹ́mù bí òkúta, àti Kédárì ó pọ̀ bí igi Síkámórè ní àwọn ẹsẹ̀ òkè Àwọn ẹsin Sólómónì ní a gbà láti ìlú òkèrè Éjíbítì àti láti kúè oníṣòwò ti ọba ni ó rà wọ́n láti Kúè Wọ́n ra kẹ̀kẹ́ kan láti Éjíbítì Fún ọgọ́rùn ún mẹ́fà Sékélì fàdákà àti ẹṣin kan fún ọgọ́rin-méjì-ó-dínláàdọ́ta Wọ́n ko wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba mìíràn ti Hítì àti ti àwọn ará Árámíà Ísírẹ́lì Sì Ṣọ̀tẹ̀ Lórí Réhóbóámù Réhóbóámù sì lọ sí Ṣékémù nítorí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lọ síbẹ̀ láti fi jẹ ọba Nígbà tí Jéróbóámù ọmọ Nébátì gbọ́ èyí ó wà ní Éjíbítì, níbi tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ ọba Sólómónì ó sì padà láti Éjíbítì Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà ó sì ránsẹ́ sí Jéróbóámù àti òun àti gbogbo àwọn Ísírẹ́lì lọ sí ọ̀dọ̀ Réhóbóámù wọ́n sì wí fún pé Baba rẹ gbé àjàgà tí ó wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìwọ mú un fúyẹ́, iṣẹ́ líle àti àjàgà wúwo tí ó gbé ka orí wa, àwa yóò sì sìn ọ́ Réhóbóámù sì dáhùn pé, ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn náà sì lọ Nígbà náà ni ọba Réhóbóámù fi ọ̀ràn lọ̀ àwọn àgbààgbà tí ó ti ń sin Baba rẹ̀ Sólómónì nígbà ayé rẹ̀, ó sì bi wọ́n léèrè pe Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe gbà mí ní ìmọ̀ràn láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn Wọ́n sì dáhùn, Tí ìwọ yóò bá ṣe rere sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kí o sì ṣe ire fún wọn kí o sì fún wọn ní ìdáhùn rere, wọn yóò sì máa jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nígbà gbogbo Ṣùgbọ́n Réhóbóámù kọ ìmọ̀ràn náà tí àwọn àgbààgbà fi fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn ọmọ ọkùnrin tí ó ti dàgbà sókè pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n sì ń dúró níwájú rẹ̀ Ó sì bèrè lọ́wọ́ wọn pé, Kí ni ìmọ̀ràn yín Báwo ni kí a ṣe dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí wọ́n wí fún mi pé, Mú kí àjàgà tí baba rẹ gbé lé wa kí ó fúyẹ́ díẹ̀   Àwọn ọ̀dọ́mọdé tí ó ti dàgbà pẹ̀lú rẹ dá a lóhùn pé, sọ fún àwọn ènìyàn tí ó wí fún ọ wí pé, Baba gbé àjàgà wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n mú àjàgà wa fúyẹ́, wí fún wọn, pé ìka ọwọ́ mi kékeré, ó nípọn ju ìbàdí baba mi lọ Baba mi gbé àjàgà wúwo ka orí yín èmi yóò sì tún mú kí ó wúwo jùlọ Baba mi fi pàṣán nà yín pẹ̀lú ẹgba Èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe   Ní ọjọ́ kẹ̀ta Jéróbóámù àti gbogbo ènìyàn sì padà sí ọ̀dọ̀ Réhóbóámù, gẹ́gẹ́ bí ọba ti sọ, Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ kẹ̀ta Ọba sì dá wọn lóhùn ní ọ̀nà líle Ó kọ̀ ìmọ̀ràn àwọn àgbààgbà, Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo Èmi yóò sì mú kí ó wúwo jùlọ Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán Èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèé Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì tẹ́tísi àwọn ènìyàn, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ tí a ti sọ fún Jéróbóámù ọmọ Nébátì nípasẹ̀ Áhíjà ará Ṣilò Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti wọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé Ìpín kí ní a ní nínú Dáfídì, ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jésè Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ìwọ Ísírẹ́lì! Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dáfídì! Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ilé wọn Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń gbé ní ìlú Júdà, Réhóbóámù pàpà ń jọba lórí wọn Ọba Réhóbóámù rán Ádónírámù jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúuru, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa Ọba Réhóbóámù bí ó tí wù kí ó rí, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jérúsálẹ́mù Bẹ́ẹ̀ ni Ísírẹ́lì sì wà ní ìsọ̀tẹ̀ lórí ilé Dáfídì títí fi di òní yìí Nígbà tí Réhóbóámù dé Jérúsálẹ́mù, ó kó ilé Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n jẹ́ ológun, láti bá Ísírẹ́lì jà kí ó lè mú ìjọba naà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Réhóbóámù Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí wá sí ọ̀dọ̀ Ṣémáíà ènìyàn Ọlọ́run Wí fún Rehóbóámù ọmọ Sólómónì ọba Júdà, sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì, Èyí ní ohun tí Olúwa wí Ẹ má ṣe gòkè lọ lati lọ jà pẹ̀lú arákùnrin yín, ẹ lọ sílé, gbogbo yín, nítorí ti ìṣe mi nìyí   Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì padà sẹ́yìn láti yan lọ dojúkọ Jéróbóámù Réhóbóámù ń gbe ní Jérúsálẹ́mù ó sì kọ́ àwọn ìlú fún ààbò ní Júdà Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Étamì, Tẹ́kóà, Beti-Súrì, sókò, Ádúlámù Gátì, Maréṣálù Ṣífì, Ádóráímù, Lákíṣì, Áṣékà Ṣórà, Áíjálónì, àti Hébírónì Wọ̀nyí ni àwọn ìlu ìdábòbò ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì Ó sì mú àwọn ìlú olódi lágbára, ó sì fi àwọn balógun sínú wọn àti àkójọ oúnjẹ, àti òróró àti ọtí wáìnì Àti ní olúkúlùkù ìlú ni ó fi àsà àti ọ̀kọ̀ sí, ó sì mú wọn lágbára gidigidi, ó sì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì lábẹ́ rẹ̀ Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì, láti gbogbo ẹ̀yà wọn jákè jádò Ísírẹ́lì wà ní ẹ̀bá rẹ̀ Àwọn ará Léfì fi ìgbéríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Júdà àti Jérúsálẹ́mù nítorí Jéróbóamù àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà Olúwa Ó sì yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn Ibi gíga àti fún ewúrẹ́ àti àwọn òrìṣà ti a gbẹ́ tí o ti ṣẹ̀ Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tẹ̀lé àwọn ará Léfì lọ sí Jérúsálẹ́mù láti lọ rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run bàbá a wọn Ó fún ìjọba Júdà ní agbára, ó sì ti Réhóbóámù ọmọ Sólómónì lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dáfídì àti Sólómónì ní àkókò yí Réhóbóámù fẹ́ Máhálátì tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ọmọkùnrin Dáfídì Jérímótì àti ti Ábíháílì, ọmọbìnrin ọmọkùnrin ti Jésè Élíábì Ó bí àwọn ọmọ fún un Jéúṣì, Ṣémáríà àti Ṣáhámì Nígbà náà ó fẹ́ Mákà ọmọbìnrin Ábúsálómù, tí ó bí Ábíjà fún Átáì, Ṣíṣà àti Ṣélómítì Réhóbóámù fẹ́ràn Mákà ọmọbìnrin Ábúsálómù ju èyí kejì nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀ lọ Ní gbogbo rẹ̀, ó ní ìyàwó méjìdínlógún àti ọgọ́ta àlè ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin Réhóbóámù yan Ábíjà ọmọ Mákà láti jẹ́ olóyè ọmọ aládé láàárin àwọn arákùnrin rẹ̀, kí ó ba à lè ṣe é ní ọba Ó hùwà ọlọ́gbọ́n, nípa fí fọ́nká díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ jákè jádò ká àwọn agbégbé Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti sí gbogbo àwọn ìlú ńlá aláàbò Ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n fẹ́, ó sì gba ọ̀pọ̀ ìyàwó fún wọn Ṣíṣákì Ṣẹ́gun Réhóbóámù Lẹ́yìn ìgbà tí a fi ipò Réhóbóámù gẹ́gẹ́ bí ọba lélẹ̀, tí ó sì ti di alágbára, òun àti gbogbo Ísírẹ́lì, pẹ̀lú rẹ̀ ni wọ́n pa òfin Olúwa tì Nítorí tí wọn kò ṣọ̀ọ́tọ́ sí Olúwa Ṣíṣákì ọba Ị́jíbítì dojúkọ Jérúsálẹ́mù ní ọdún karùnún ti ọba Réhóbóamù Pẹ̀lú ẹgbẹ̀fà kẹ̀kẹ́ àti ọkẹ́ mẹ́ta àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin àti àìníye ọ̀wọ́ ogun ti Líbíyánì, Ṣúkísè àti Kúṣì, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti Éjíbítì Ó fi agbára mú àwọn ìlú ààbò ti Júdà, pẹ̀lú wá sí Jérúsálẹ́mù bí ó ti jìnnà tó Nígbà naà, wòlíì Ṣémáíà wá sí ọ̀dọ̀ Réhóbóámù àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí Júdà tí wọ́n ti péjọ ní Jérúsálẹ́mù nítorí ìbẹ̀rù Ṣíṣáki, ó sì wí fún wọn pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí ìwọ ti pa mí tì nítorí náà èmi náà ti pa yín tì sí ọ̀dọ̀ Ṣíṣákì Àwọn olórí Ísírẹ́lì àti ọba rẹ̀ ará wọn sílẹ̀, wọ́n sì wí pé, Olódodo ni Olúwa Nígbà tí Olúwa ríi pé, wọ́n ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa yí tọ Ṣémáíà lọ pé Níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Èmi kì yóò pa wọ́n ṣùgbọ́n, yóò fún wọn ní ìtúsílẹ̀ tó bá yá Ìbínú mi kì yóò dà sórí Jérúsálẹ́mù ní pasẹ̀ Ṣíṣákì Bí ó ti wù kí ó rí, wọn yóò sìn ní abẹ́ rẹ̀, kí wọn kí ó lè mọ̀ ìyàtọ̀ láàárin sísìn mí àti sísin àwọn ọba ilẹ̀ mìíràn Nígbà tí Ṣíṣákì ọba Éjíbítì dojúkọ Jérúsálẹ́mù, ó gbé àwọn ìṣúra ilé Olúwa , àti àwọn ìsúra ààfin ọba Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Sólómónì dá Bẹ́ẹ̀ ni, ọba Réhóbóámù dá àwọn àpáta idẹ láti fi dípò wọn, ó sì fi èyí lé àwọn alákòóso àti olùsọ́ tí ó wà ní ẹnu isẹ́ ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà ààfin ọba lọ́wọ́ Ìgbàkígbà tí ọba bá lọ sí ilé Olúwa , àwọn olùsọ́ n lọ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn apáta naà àti lẹ́yìn, wọ́n dá wọn padà sí yàrá ìṣọ́ Nítori ti Réhóbóámù rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìbínú Olúwa yí padà kúrò lórí rẹ̀, a kò sì paárun pátapáta Nítòótọ́, ire díẹ̀ wà ní Júdà Ọba Réhóbóámù fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi ní Jérúsálẹ́mù, ó sì tẹ̀ ṣíwájú gẹ́gẹ́ bí ọba Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì nígbà tí ó di ọba Ó sì jọba fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ní Jérúsálẹ́mù, ìlú ńlá tí Olúwa ti yàn jáde kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní èyí tí ó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ sí O sì ṣe búburú, nítorí tí kò múra ọkàn rẹ̀ láti wá Olúwa Fún tí iṣẹ́ ìjọba Réhóbóámù láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìrantí ti Ṣémáíà wòlíì àti ti Idò, aríran tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá Ìtẹ̀ṣíwájú ogun jíjà sì wà láàárin Réhóbóámù àti Jéróbóámù Réhóbóámù sinmi sínú ìlú ńlá ti Dáfídì Ábíjà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ọ̀tẹ̀ Wà Láàrin Ábíjà Àti Jéróbóámù Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jéróbóámù, Ábíjà di ọba Júdà Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́ta Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Mákà, ọmọbìnrin Úríélì ti Gíbéà Ogun wà láàárin Ábíjà àti Jéróbóámù Ábíjà lọ sí ojú ogun pẹ̀lu àwọn ọmọ ogun ogún ọ̀kẹ́ ọkùnrin alágbára, Jéróbóámù sì fa ìlà ogun sí i pẹ̀lu ogójì ọ̀kẹ́ ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára Ábíjà dúró lórí òkè Ṣémáráímù ní òkè orílẹ̀ èdè Éfiráímù, ó sì wí pé, Jéróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ mi! Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé Olúwa Ọlọ́run fún Dáfídì àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀ Síbẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, oníṣẹ́ Sólómónì ọmọ Dáfídì, ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀gá rẹ̀ Àwọn ènìyàn lásán aláìwúlò péjọ yí i ká, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Réhóbóámù ọmọ Sólomónì ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fún ra rẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n Nísinsìn yìí, ìwọ ṣètò láti kọ́ ìjọba Olúwa , tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé Dáfídì Ìwọ jẹ́ ọmọ ogun tí ó gbilẹ̀, ìwọ sì ní pẹ̀lu rẹ ẹgbọrọ màlúù wúrà ti Jéróbóámù dà láti se Ọlọ́run yín Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ kò lé àwọn àlùfáà Ọlọ́run jáde, àwọn ọmọ Árónì àti àwọn ará Léfì Tí ó sì se àwọn àlùfáà ti ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ti ṣe Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò méjì lè jẹ́ àlùfáà èyí tí kì í ṣe àwọn Ọlọ́run Ní ti àwa, Olúwa ni Ọlọ́run wa, àwa kò sì ti ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Àwọn àlùfaà tí ó ń sin Olúwa jẹ́ àwọn ọmọ Árónì àwọn ará Léfì sì n ràn wọ́n lọ́wọ́ Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ọrẹ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú Olúwa Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́ A ń pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa mọ́ Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa òun ni olórí wa Àwọn àlùfáà rẹ̀ pẹ̀lú fèrè wọn yóò dún dídùn ogun sí i yín Ẹyin ọkùnrin Ísírẹ́lì, Ẹ má ṣe dojú ìjà kọ Olúwa Ọlọ́run baba a yín nítorí ẹ̀yin kì yóò yege Nísinsìn yìí, Jéróbóámù ti rán àwọn ọ̀wọ́ ogun lọ yíká láti jagun ẹ̀yìn Kí ó lè jẹ́ pé, tí òun bá wà ní wájú Júdà, bíba ní bùba á wà ní ẹ̀yìn wọn Nígbà tí Júdà sì bojúwo ẹ̀yìn, sì kíyèsi i, ogun ń bẹ níwáju àti lẹ́yìn, wọn sì ké pe Olúwa , àwọn àlùfáà sì fun ìpè Olúkúlùkù, ọkùnrin Júdà sì hó ó sì ṣe, bí àwọn ọkùnrin Júdà sì ti hó, ni Ọlọ́run kọlu Jéróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì níwájú Ábíjà àti Júdà Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sálọ kúrò níwájú Júdà, Ọlọ́run sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́ Ábíjà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ìdàmú ńlá jẹ wọ́n ní ìyà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ọkùnrin tí a yàn ṣubú ní pípa nínú Ísírẹ́lì Báyìí ni a rẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní àkókò náà, àwọn ọmọ Júdà sì borí nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn Ábíjà sì lépa Jéróbóámù, ó sì gba ìlú lọ́wọ́ rẹ̀, Bétílì pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Jeṣánà pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Éufúráímù pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ní Jéróbóámù kò sì tún ní agbára mọ́ ní ọjọ́ Ábíjà Olúwa sì lù ú ó sì kú Ábíjà sì di alágbára, ó sì gbé obìnrin mẹ́talá ní ìyàwó, ó sì bi ọmọkùnrin méjìlélógún, àti ọmọbìnrin mẹ́rìndinlógún Àti ìyókù ìṣe Ábíjà, àti ìwà rẹ̀, àti iṣẹ́ rẹ̀, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtumọ̀ Ididì, wòlíì Ídò Ásà Ọba Júdà Ábíjà sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín sínú ìlú ńlá ti Dáfídì Ásà ọmọ rẹ̀ rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, orílẹ̀ èdè wà ní àlàáfíà fún ọdun mẹ́wàá Ásà ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́ ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ Ó gbé àwọn pẹpẹ àjèjì kúrò àti àwọn ibi gíga Ó fọ́ àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ̀, ó sì gé àwọn òpó Áṣérà bolẹ̀ Ó pa á láṣẹ fún Júdà láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wọn àti láti tẹ̀lé àwọn òfin rẹ̀ àti àṣẹ Ó gbé àwọn ibi gíga kúrò àti àwọn pẹpẹ tùràrí ní gbogbo ìlú ní Júdà Ìjọba sì wà ní àlàáfíà ní abẹ́ rẹ̀ Ó mọ àwọn ìlu ààbò ti Júdà, níwọ̀n ìgbà tí ìlú ti wà ní àlàáfíà Kò sí ẹnikẹ́ni ti o jagun pẹ̀lu rẹ̀ nígbà àwọn ọdun wọ̀n yẹn Nítorí Olúwa fún un ní ìsinmi Ẹ jẹ́ kí a kọ́ àwọn ìlú wọ̀nyí Ó wí fún Júdà, Kí ẹ sì mọ odi yí wọn ká pẹ̀lú àwọn ile ìṣọ́ gíga, àwọn ẹnu ọ̀nà òde, àti àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ Ilé náà ti wà, nítorí a ti bèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run wa a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ti fún wa ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kọ́ ọ, wọn sì ṣe rere Ásà ní àwọn ọmọ ogun ti ó jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àwọn ọkùnrin láti Júdà Pẹ̀lú àwọn ohun èlò àwọn àpáta ńlá àti ọ̀kọ̀ àti ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá láti Béńjamẹ́nì wọ́n dira pẹ̀lú àwọn apata kékèké àti àwọn ọrun Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ògbójú jagunjagun ọkùnrin Ṣérà ará Kúṣì yàn láti dojú kọ wọ́n, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọmọ ogun pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́ta kẹ̀kẹ́, wọ́n sì wá láti jìnnà réré bí Máréṣà Ásà jáde lọ lati lọ bá a Wọ́n sì mú ibi ogun ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣéfátanì lẹ́bá Máréṣà Nígbà náà, Ásà ké pe Olúwa Ọlọ́run baba a rẹ̀, ó sì wí pé Olúwa kò sí ẹnìkan bí ì rẹ láti rán aláìlágbára lọ́wọ́láti dójú kọ ẹni ńlá Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run wa, nítorí tí àwa gbẹ́kẹ̀ lé ọ àti ní orúkọ rẹ ni àwa fi wá láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun yìí Olúwa , ìwọ ni Ọlọ́run wa má se jẹ́ kí ènìyàn kó ṣẹ́gun rẹ Olúwa lu àwọn ará Kúsì bolẹ̀ níwájú Ásà àti Júdà Àwọn ará Kúsà sá lọ Ásà àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sá tẹ̀lé wọn ní jìnnà réré sí Gérárì Ọ̀pọ̀lọpọ̀, àwọn ará Kúṣì ṣubú, wọn kò sì le sán padà mọ́ A fún wọn pa níwájú Olúwa àti ọmọ ogun rẹ̀ Àwọn ọkùnrin Júdà kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógún Wọ́n pa gbogbo àwọn ìletò tí ó wà ní ẹ̀bá Gérárì, nítorí tí ìpayà Olúwa ti sọ̀kalẹ̀ sórí wọn Wọ́n kó gbogbo ìkógún àwọn ìletò yìí lọ, níwọ̀n ìgbà tí ọ̀pọ̀ ìkógun ti wà níbẹ̀ Wọ́n kọ lu àwọn ibùdó àwọn darandaran, wọ́n sì gbé àwọn ọ̀wọ́-ẹran àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ àti àwọn ìbákasẹ Nígbà náà wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù Àtúnṣe Ásà Ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Ásáríyà ọmọ Ódédì Ó jáde lọ bá Ásà, ó sì wí fún un pé, Tẹ́tí si mi Ásà, àti gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nígbà tí ìwọ bá wà pẹ̀lú rẹ̀ Ti ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i ní ẹ̀bá rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ silẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Fún ọjọ́ pípẹ́ ni Ísírẹ́lì ti wà láì sin Ọlọ́run òtitọ́, àti láìní àlùfáà ti ń kọ́ ni, àti láì ní òfin Ṣùgbọ́n nínú ìpọ́njú wọn, wọ́n yí padà si Olúwa Ọlọ́run Isírẹ̀lì, wọ́n sì wa kiri Wọ́n sì ri i ní ẹ̀gbẹ́ wọn Ní ọjọ́ wọ̀nnì ó léwu kí ènìyàn máa rìn ìrìnàjò kiri, nítorí tí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà wà nínú làálàá ńlá Orílẹ̀-èdè kan ń run èkejì àti ìlu kan sí òmíràn nítorí Olúwa ń yọ wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìpọ́njú Ṣùgbọ́n fun ìwọ, jẹ́ alágbára, kí ó má sì se sú ọ Nítorí tí a ó fi èrè sí iṣẹ́ ẹ̀ rẹ Nígbà tí Ásà gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti àsọtẹ́lẹ̀ Ásáríyà ọmọ Ódédì wòlíì, ó mú àyà rẹ̀ le Ó gbé àwọn òrìsà ìkóríra kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti kúrò nínú àwọn ìlú tí ó ti fi agbára mú ní ori òkè Éfúráímù Ó tún pẹpẹ Olúwa ṣe tí ó wà ní iwájú Pórífíkò ti ilé Olúwa Nígbà naà, ó pe gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ àti àwọn ènìyàn láti Éfúráímù, Mánásè àti Síméónì tí ó ti ṣe àtìpó ní àárin wọn Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Ísírẹ́lì nigbà tí wọ́n rí i wí pé Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀ Wọ́n péjọ sí Jérúsálẹ́mù ní oṣù kẹta ọdún kẹẹ̀dógún ti ìjọba Ásà Ní àkókò yìí, wọ́n rúbọ sí Olúwa ọgọ́rùnún méje akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún ḿéje àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ láti ibi ìkogun tí wọ́n ti kó padà Wọ́n sì tún dá májẹ̀mú láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn tinútinú wọn àti tọkàntọkàn wọn Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Olúwa Ọlọ́run Isirẹ́lì, pípa ni á ó paá láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin Wọ́n sì búra ní ohùn rara fún Olúwa àti pẹ̀lú ìhó nla àti pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú fèrè Gbogbo Júdà yọ̀ nípa ìbúra náà nítorí wọ́n ti búra tinútinú wọn wọ́n sì fi gbogbo ìfẹ́ inú wọn wá a, wọ́n sì rí i, Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi yí káàkiri Ọba Ásà rọ ìyá ńlá rẹ̀ Mákà lóyè láti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyá ọba nítorí tí ó ti ṣe òpó Áṣérà tí ń lé ni sá Ásà gé òpó náà lulẹ̀, wòó, ó sì jóo ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì Ṣùgbọ́n a kò mú àwọn ibi gíga náà kúrò ní Ísírẹ́lì síbẹ̀síbẹ̀ ọkàn Ásà wà ní pípé ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo Ó sì mú àwọn ohun mímọ́ náà ti baba rẹ̀ àti àwọn ohun mímọ́ ti òun tìkára rẹ̀ tirẹ̀ wá sínú ilé Ọlọ́run, wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò náà Kò sí ogun mọ́ títí fún ọdún márùndínlógójì ti ìjọba Ásà Ìgbẹ̀yìn Ọdún Ásà Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìjọba Ásà, Básà ọba Ísírẹ́lì gòkè wá sí Júdà ó sì kọlu Rámà, láti ma bàá jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè jáde tàbí wọlé tọ Ásà ọba Júdà lọ Nígbà náà ni Ásà mú wúrà àti fàdákà jáde ninú ilé ìsúra ilé Olúwa àti ààfin ọba ó sì ránsẹ́ sí Bẹni-Hádádì ọba Árámù, ẹni tí ń gbé ní Dámásíkù, ó wí pé, Májẹ̀mu kan wà láàrin èmi àti ìrẹ, bí ó ti wà láàrin baba mi àti baba rẹ Ẹ wò ó, mo fi wúrà àti fàdákà ránsẹ́ sí ọ lọ, ba májẹ̀mu tí o bá Básà ọba Ísirẹ́lì dá jẹ́, kí ó lè lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi Bẹni-hádádì sì gbọ́ ti Ásà ọba, ó sì rán àwọn olórí ogun rẹ̀ lọ sí àwọn ìlú Ísírẹ́lì, wọ́n sì kọlu Íjónì, Dánì, Abeli-Máímù, àti gbogbo ilú ìsúra Náfítalì Nígbà tí Básà gbọ́ èyi, ó sì dá kíkọ́ Rámà dúró, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró Nígbà náà ní ọba Ásà kó gbogbo àwọn ènìyàn Júdà jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rámà lọ èyí ti Básà ń fi kọ́lé ó sì fi kọ́ Gébà àti Mísípà Ní àkókò náà wòlíì Hánánì wá sí ọ̀dọ̀ Ásà ọba Júdà, ó sì wí fún un pé, nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé ọba Árámù, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Árámù ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ Àwa kì í ṣe ará Etiópíà àti àwọn ará Líbíà àwọn alágbára ogun pẹ̀lu ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin Síbẹ̀ nígbà tí ìwọ bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò sì fi wọ́n lé ọwọ́ rẹ Nítorí ojú Olúwa yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun Ásà sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú Ní àkókò náà Ásà sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára Àwọn iṣẹ́ ìjọba Ásà, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Júdà àti Ísírẹ́lì Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba rẹ̀, Ásà sì ṣe àìsàn pẹ̀lú àrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀ Lákókò àrùn rẹ̀ ó múná, kó dà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa , ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan Nígbà náà tí ó pé ọdún kọ́kànlélógójì rẹ̀, Ásà kú, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn ìjọba baba rẹ̀, Wọ́n sì sin ín sínú ìsà òkú tí ó ti gbé jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dáfídì Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dìdùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n àwọn alápòlù pèsè, wọ́n sì ṣe ìjóná ńlá nínú ọlá ńlá rẹ̀ Jehóṣáfátì Ọba Júdà Jehóṣáfátì ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀ ó sì mú arà rẹ̀ lágbára sí lórí Ísírẹ́lì Ó sì fi ogun sínú gbogbo ìlú olódi Júdà ó sì kó ẹgbẹ́ ológun ní Júdà àti nínú ìlú Éfúráímù tí baba rẹ̀ ti gbà Olúwa sì wà pẹ̀lú Jéhóṣáfátì nítorí, ní ọdún àkọ́kọ́ rẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà ti baba rẹ̀ Dáfídì ti rìn, kò sì fi ọ̀ràn lọ Báálímù Sùgbọ́n ó wá Ọlọ́run baba rẹ̀ kiri ó sì tẹ̀lẹ́ àṣẹ rẹ̀ ju iṣẹ́ Ísírẹ́lì Olúwa sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Júdà sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehóṣáfátì, Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọpọ̀ Ọkàn rẹ̀ sì gbé sokè si ọ̀nà Olúwa , pẹ̀lúpẹ̀lù, ó sì mú ibi gíga wọn àti òrìṣà kúrò ní Júdà Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ Bẹni-Háílì, Obádíà Sekaríà, Nètaníélì Míkíà láti máa kọ́ ni nínú ìlú Júdà Wọ́n sì ní díẹ̀ lára àwọn ọmọ Léfì, àní Ṣémáyà, Netaníà, Sebadíà, Ásáélì, Ṣémírámótì, Jéónátanì, Àdóníjà, Tóbíyà àti Tobi-Àdóníjà àti àwọn àlùfáà Élíṣámà àti Jéhórámù Wọ́n ń kọ́ ni ní agbégbé Júdà, wọ́n mú ìwé òfin Olúwa dání, wọ́n sì rìn yíká gbogbo àwọn ìlú Júdà wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn Ìbẹ̀rù Olúwa bà lórí gbogbo ìjọba ilẹ̀ tí ó yí Júdà ká, débi pé wọn kò bá Jéhóṣáfátì jagun Lára àwọn ará Fílístínì, mú ẹ̀bùn fàdákà gẹ́gẹ́ bí owó ọba wá fún Jéhóṣáfátì, àwọn ará Árábíà sì mú ọ̀wọ́ ẹran wá fún-un, ẹgbàrin ó dín ọ̀dúnrún àgbò àti ẹgbarìndín ní ọ̀ọ́dúnrún òbúkọ Jéhóṣáfátì sì ń di alágbára nínú agbára síi, ó sì kọ́ ilé olódi àti ilé ìsúra púpọ̀ ní Júdà Ó sì ní ìṣúra ní ìlu Júdà Ó sì tún ní àwọn alágbára jagunjagun akọni ọkùnrin ní Jérúsálẹ́mù Iye wọn gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn nì wọ̀nyí Láti Júdà, àwọn olórí ìsùkan ti ẹgbẹ̀rún Ádínà olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dó gún alágbára akọni ọkùrin Èkejì Jéhósáfátì olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá ọkùnrin Àtẹ̀lé Ámásíà ọmọ Síkírì, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ Olúwa pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá Láti ọ̀dọ̀ Bẹ́ńjámínì Élíádà, alágbára akọni ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá àwọn jagunjagun ọkùnrin pẹ̀lú ọrun àti àpáta ìhámọ́ra Àtẹ̀lé Jéhósábádì, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án jagunjagun ọkùnrin múra sílẹ̀ fún ogun Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ń dúró níwáju ọba, ní àyíká àwọn ẹni tí ó fi sínú ìlú olódi ní àyíká gbogbo Júdà Mikáyà Sọtẹ́lẹ̀ Lórí Áhábù Nísinsin yìí Jéhóṣáfátì sì ní ọrọ̀ àti ọlá púpọ̀, ó sì dá àna pẹ̀lú Áhábù nípa fífẹ́ ọmọ rẹ̀ Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó sọ̀kalẹ̀ láti lọ bá Áhábù lálejò ní Saaríà Áhábù sì pa àgùntàn àti màlúù púpọ̀ fún àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ó sì rọ̀ọ́ láti dojú ìjà kọ Ramótì Gílíádì Áhábù ọba Ísírẹ́lì sì béèrè lọ́wọ́ ọba Jèhóṣáfátì, ọba Júdà pé, Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi sí Rámótì Gílíádì Jehóṣáfátì sì dá a lóhùn pé, Èmi wà gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe wà, àti àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ àwa yóò pẹ̀lú rẹ ninú ogun naà Ṣùgbọ́n Jehóṣáfátì náà sì tún wí fún ọba Ísírẹ́lì pé, Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Olúwa Bẹ́ẹ̀ ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì papọ̀, irínwó ọkùnrin ó sì bi wọ́n pé, Kí àwa kí lọ sí ogun Rámótì Gélíádì tàbi kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ Lọ, wọ́n dáhùn, nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́ Ṣùgbọ́n Jehósáfátì béèrè pé, Ṣé kò ha sí wòlíì Olúwa níbí ẹni tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ Ọba Ìsírélì dá Jehóṣáfatì lóhùn pé, Ọkùnrin kan wà síbẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ì bá tún béèrè lọ́wọ́ Olúwa , ṣùgbọ́n èmi kórìíra rẹ̀ nítorì kò jẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere kan nípa mi ṣùgbọ́n bí kò ṣe ohun búburú, ní gbogbo ìgbà òun náà ni Míkáyà ọmọ Ímílà Ọba kò gbọdọ̀ sọ bẹ́ẹ̀, Jehóṣáfátì sì dá lóhùn Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì pe ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ó sì wí pé, Ẹmú Míkáyà ọmọ Ímílà kí ó yára wá Wọ́n wọ aṣọ Ìgúnwà wọn, ọba Ísírẹ́lì àti Jehóṣáfátì ọba Júdà wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ́n ní ìta ẹnu bodè Samaríà, pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn Nísinsin yìí Sedekáyà ọmọ Kénánà sì ti ṣe ìwo irin, ó sì wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa sọ pẹ̀lú èyí ìwọ yóò kan àwọn ará Síríà títí ìwọ ó fi pa wọ́n run Gbogbo àwọn wòlíì tí ó kù ni wọn ń sọtẹ̀lẹ́ ní àkókò kan náà, Wọ́n sì wí pé, dojúkọ Rámótì Gílíádì ìwọ yóò sì ṣẹ́gun, wọ́n wí pé, nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́ Ìránsẹ́ tí ó ti lọ pe Míkáyà sì wí fún un pé, Ẹ wò ó, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan àti òmíràn wòlíì fi ẹnu kan sọ rere fún ọba Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kí ó níí ṣe pẹ̀lú ti wa, kí o sì sọ rere Ṣùgbọ́n Míkáyà wí pe, Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa ń bẹ láàyè, èmi yóò sọ ohun tí Ọlọ́run mi sọ Nígbà tí ó dé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, Míkáyà, se kí àwa ki ó lọ sí ogun ti Rámótì Gílíádì, tàbí kí àwa kí ó fàsẹ́yìn Ẹ dojú kọ wọ́n kí ẹ sì ṣẹ́gun Ó dahùn, nítorí a ó fi wọ́n lé yín lọ́wọ́ Ọba sì wí fún-un pé, Ìgbà mélòó ni èmi ó fi ọ́ búra láti sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní orúkọ Olúwa Nígbà náà Míkáyà dáhùn, Mo rí gbogbo Ísírẹ́lì fọ́n káàkiri lórí àwọn òkè, bí àgùntàn tí kò ní olùsọ́ Olúwa sì wí pé, Àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò ní ọ̀gá Jẹ́ kí olúkúlùkù lọ sí ilé ní àlàáfíà   Ọba Ísírẹ́lì wí fún Jéhóṣáfátì pé, Ṣe èmi kò sọ fún ọ wí pé òun kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kankan nípa mi rí, ṣùgbọ́n búburú nìkan Mikáyà tẹ̀ṣíwájú pé, Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Mo rí Olúwa jòkó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lápá ọ̀tún àti lápá òsì Olúwa sì wí pé, Ta ni yóò tan Áhábù ọba Ísírẹ́lì lọ sí Rámátì Giléádì kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀ Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún Ní ìparí, ni ẹ̀mí kan wá ṣíwájú, ó dúró níwájú Olúwa ó sì wí pé, Èmi yóò tàn án  Nípa ọ̀nà wo Olúwa beèrè  Èmi yóò lọ láti lọ di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì Ó wí pé  Ìwọ yóò sì borí nínú ìtànjẹ rẹ̀ báyìí, ni Olúwa wí Lọ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìn yìí Olúwa ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu àwọn wòlíì rẹ Olúwa sì ti sọ ibi sí ọ Nígbà náà Sedékíà ọmọ Kénánà lọ sókè ó sì gbá Míkáyà ní ojú Ní ọ̀nà wo níi ẹ̀mí Olúwa gbà kọjá lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀ Ó sì bèèrè Míkáyà sì dáhùn pé, ìwọ yóò ṣe ìwadìí ní ọjọ́ tí ìwọ yóò sápamọ́ sínú ìyẹ̀wù Ọba Ísírẹ́lì paálásẹ pé, Mú Mikáyà kí o sì ran padà sí Ámónì olóri ìlú àti sí Jóáṣì ọmọ ọba, Ó sì wí pé Èyí ni ohun tí ọba sọ ẹ fi ènìyàn yìí sínú túbú kí ẹ má sì ṣe fún-un ní ohunkóhun ṣùgbọ́n àkàrà àti omi títí tí èmi yóò fi dé ní àlàáfíà   Míkáyà sì wí pe, Tí ìwọ bá padà ní àlàáfíà, Olúwa kò sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi Nígbà náà, ó sì fi kún-un pé, Ẹgbọ́ ọ̀rọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn! Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì àti Jéhóṣáfátì ọba Júdà lọ sókè ní Rámótì Gílíádì Ọba Ísírẹ́lì sọ fún Jéhóṣáfátì pé, Èmi yóò lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ wọ aṣọ ìgunwà rẹ Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì pa aṣọ rẹ̀ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà Nísinsìn yìí ọba Síríà ti pàsẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Ẹ má ṣe jà pẹ̀lú ẹnìkankan, èwe tàbí àgbà àyàfi ọba Ísírẹ́lì Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rí Jéhóṣáfátì, wọ́n rò wí pé, Èyí ní ọba Ísírẹ́lì Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yípadà láti bá a jà Ṣùgbọ́n Jéhóṣáfátì kégbe sókè, Olúwa sì ràn án lọ́wọ́ Ọlọ́run sì lé wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Ó sì ṣe, nígbà tí olórí kẹ̀kẹ́ ríi wí pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, wọ́n sì dáwọ́ lílé rẹ̀ dúró Ṣùgbọ́n ẹnìkan fa ọrun rẹ̀ láì pète, ó sì bá ọba Ísírẹ́lì láàárin ìpàdé ẹ̀wù ìrin, ọba sì sọ fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì wà mí jáde kúrò lójú ìjà Nítorí èmi ti gbọgbẹ́ Ní ọjọ́ pípẹ́, ìjà náà sì ń pọ̀ síi, ọba Ísírẹ́lì dúró nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ kọjú sí àwọn ará Síríà títí ó fi di àsaálẹ́ Lẹ́yìn náà ní àkókò ìwọ oòrùn, ó sì kú Jéhù Bá Jéhóṣáfátì Wí Nígbà tí Jéhóṣáfátì ọba Júdà padà ní àlàáfíà sí ilé rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù, Jéhù aríran, ọmọ Hánánì jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, Sé ìwọ yóò máa ran ènìyàn búburú lọ́wọ́, kí o sì fẹ́ràn àwọn tí ó kórìíra Olúwa Nítorí èyí, ìbínú Olúwa wà lórí wa Bí ó ti wù kí ó rí, ohun rere wà nínú rẹ, nítorí tí ìwọ ti mú àwọn ilé àwọn ère òrìṣà kúrò, tí o sì múra ọkàn rẹ láti wá Ọlọ́run Jéhóṣáfátì sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù ó sì jáde lọ padà láàárin àwọn ènìyàn láti Béríṣébà dé òkè ìlú Éfúráímù, ó sì mú wọn padà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run baba wọn Ó sì yan àwọn onídàájọ́ sí ilẹ̀ náà, ní olúkúlùkù ìlú olódi, Júdà Ó sì wí fun wọ́n pé, Ẹ kíyèsí ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa , ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́ Nísinsin yìí jẹ́kí ìbẹ̀rù Olúwa kí ó wá sí orí rẹ̀ Ṣe ìdájọ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nítorí pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run kò sí àìṣedéédéé tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ Ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú, Jéhóṣáfatì yan díẹ̀ lára àwọn Léfì, àwọn àlùfáà àti àwọn olórí ìdílé Ísírẹ́lì si pípa òfin Olúwa mọ́ àti láti ṣe ìdájọ́ Wọn sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù Ó sì kìlọ̀ fún wọn wí pé Ìwọ gbọdọ̀ sìn pẹ̀lú òtítọ́ àti pẹ̀lú ọkàn pípé ní ìbẹ̀rù Olúwa Ní gbogbo ẹjọ́ tí ó bá wà níwájú rẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin yín tí ń gbé ìlú wọn bóyá ẹ̀jẹ̀ tí ń ṣàn tàbí ìyókù òfin pẹ̀lú, paálásẹ ìlànà àti ẹ̀tọ́, ìwọ gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn láti má ṣe dẹ́sẹ̀ sí Olúwa bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú yóò sì wá sórí yín, àti sórí àwọn arákùnrin Ṣe èyi, ìwọ kò sì ní dẹ́ṣẹ̀ Ámáríyà àlùfáà ni yóò jẹ́ olórí yín nínú gbogbo ọ̀ràn tí ó jẹ́ ti Olúwa , àti Ṣébádíà ọmọ Íṣímáélì alákòóso ìdílé Júdà, ní yóò jẹ́ olórí ní gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba, àti àwọn ará Léfì pẹ̀lu yin yóò sìn gẹ́gẹ́ bí ìjòyè níwájú yín Ẹ ṣeé pẹ̀lú ìmọ́kànle, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú àwọn tó bá ń ṣe rere Àwọn Ètò Fún Kíkọ́ Ilé Sólómónì pinnu láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa àti ilé kan fún ìjọba rẹ̀ Sólómónì sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin àwọn ọkùnrin láti ru ẹrù àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rin àwọn ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn Sólómónì rán iṣẹ́ yìí sí Hírámíà ọba Tírè Rán àwọn igi kédárì sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe fún baba à mi Dáfídì Nígbà tí ó fi igi kédárì ránsẹ́ sí i láti kọ́ ààfin tí ó ń gbé Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà-ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún síse ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti òṣùpá tuntun àti ní àpèjọ Olúwa Ọlọ́run wa Èyí ni àsẹ fún Ísírẹ́lì láéláé Ilé Olúwa tí èmi yóò kọ́ yóò tóbi, nítorí pé Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn Ọlọ́run mìíràn lọ Ṣùgbọ́n ta ni ó le è kọ́ ilé fún Olúwa , níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀run, àní ọ̀run tí ó ga jùlọ, kò ti le è gbà á Ta ni èmi nígbà náà láti kọ́ ilé fún Olúwa , àyàfi ibi kan fún sísun ẹbọ níwájú rẹ̀ Nítorí náà, rán ọkùnrin kan sí mi, tí a kọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti idẹ àti irin, àti ní àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti ní awọ̀ oju ọ̀run, tí ó jẹ́ onímọ̀ nínú isẹ́ igi gbígbẹ́ láti ṣiṣẹ́ ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn onímọ̀ oníṣọ̀nà tí Baba à mi Dáfídì pèsè Fi igi òpépé ránṣẹ́ sí mi, pínì àti lígúmì àwọn igi láti Lébánónì, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́ Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ Láti pèsè ọ̀pọ̀ igi rírẹ́ fún mi, nitorí ilé Olúwa tí mo kọ́ gbọdọ̀ tóbi kí o sì lógo púpọ̀ Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin onígi tí ó ń gé rírẹ́ náà ni ẹgbẹ̀rún kórísì , àlìkámà ilẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún kórísì ti bálì ẹgbẹ́rùn lọ́nà ogún ìwẹ̀ ọtí wáìnì àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ìwẹ̀ òróró Ólífì Hírámù ọba Tírè fèsì padà nípasẹ̀ ìwé sí Sólómónì Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti se ọ́ ní ọba wọn Hírámì fi kún un pe Ìyìn ni fún Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó dá ọ̀run òun ayé! O ti fún ọba Dáfídì ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó kún fún ìmọ̀ àti àkíyèsí, tí yóò kọ́ ilé fún Olúwa àti ààfin fún ara rẹ̀ Èmi ń rán Húrámì-Abi, sí ọ ọkùnrin tí ó kún fún ìmọ̀ ńlá, Ẹni tí ìyá rẹ̀ wá láti Dánì àti tí Baba a rẹ̀ wá láti Tírè A kọ́ ọ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti igi, àti pẹ̀lú àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ ọ̀run àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó dára Ó ní ìmọ̀ nínú gbogbo oríṣìí iṣẹ́ fínfín Ó sì le ṣe àwárí irú ẹ̀yà kẹ́yà tí a bá fún un Òun yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn oníṣọ̀nà pẹ̀lú àwọn ènìyàn Olúwa mi, Dáfídì baba a rẹ Nísinsin yìí, jẹ́ kí Olúwa mi rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àlìkámọ̀ àti bálì àti òróró Ólífì náà àti ọtí tí ó ti ṣe ìlérí Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lébanónì tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi òkun lọ sí Jópà Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù Sólómónì ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Ísírẹ́lì lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dáfídì ti ṣe a sì ka iye wọn sí ọ̀kẹ́mẹ́jọ ó dín egbéjì-lélọ́gbọ̀n Ó sì yan ẹgbàá márùndínlógójì nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbéjìdínlógún alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣíṣẹ́ Jéhóṣáfátì Pa Móábù Àti Ámónì Run Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Édómù wá láti gbé ogun tọ Jéhóṣáfátì wá Àwọn díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin wá láti sọ fún Jéhóṣáfátì, Àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ogun ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Édómù, láti apákejì òkun Ó ti wà ní Hásásónì Támárì náà Ní ìdágìrì, Jéhóṣáfátì pinnú láti wádìí lọ́wọ́ Olúwa , ó sì kéde ààwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Júdà Àwọn ènìyàn Júdà sì kó ara wọn jọpọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Júdà láti wá a Nígbà náà Jéhóṣáfátì dìde dúró níwájú àpèjọ Júdà àti Jérúsálẹ́mù ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun O sì wí pé Olúwa , Ọlọ́run àwọn bàba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run Ìwọ ń ṣe alákòóṣo lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀ èdè Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú Ìwọ Ọlọ́run wa, ṣé o kò lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwajú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì tí o sì fi fún àwọn ọmọ Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ láéláé Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé, Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-àrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sunkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa Ìwọ yóò sì gbà wá là Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí àwọn ọkùnrin nìyí láti Ámónì, Móábù àti òkè Séírì, agbègbè ibi ti ìwọ kò ti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyè láti gbógun tì nígbà tí wọn wá láti Éjíbítì Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, wọn kò sì pa wọ́n run Sì kíyèsí i, bí wọ́n ti san án pada fún wa láti wá lé wa jáde kúrò nínú ìní rẹ, tí ìwọ ti fi fún wa láti ní Ọlọ́run wa, ṣé ìwọ kò ní ṣe ìdájọ́ fún wọn Nítorí àwa kò ní agbára láti dojú kọ àwọn ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí tí ń bọ̀ wá kó wa Àwa kò mọ̀ ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa wà ní ọ̀dọ̀ rẹ Gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà, pẹ̀lú àwọn aya wọn àti ọmọ wọn àti àwọn kékèké, dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa Nígbà náà, ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jáhásíẹ̀lì ọmọ Sékáríà, ọmọ Bénáyà, ọmọ Jéíèlì, ọmọ Mátaníyà ọmọ Léfì àti ọmọ Ásáfù, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe dìde dúró láàrin àpèjọ ènìyàn Ó sì wí pé, Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ọba Jéhóṣáfátì àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù! Èyí ní ohun tí Olúwa sọ wí pé kí a ṣe Ẹ má ṣe bẹ̀rù tàbí fòyà nítorí ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí Nítorí, ogun ìjà náà kìí ṣe ti yín, ṣùgbọ́n ti Ọlọ́run ni Ní ọla, ẹ sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ, wọn yóò gòkè pẹ̀lú ibi ṣíṣe wa, ẹ̀yin yóò sì rí wọn ní ìpẹ̀kun odò náà, níwájú ihà Jérúẹ́lì Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà Ẹ dúró ní àyè yín Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Olúwa tí yóò fi fún yín, ìwọ Júdà àti Jérúsálẹ́mù Ẹ má ṣe bẹ̀rù Ẹ má sì ṣe fòyà Ẹ jáde lọ láti lọ dojú kọ wọ́n ní ọ̀la, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú yín   Jóhóṣáfátì tẹ orí rẹ̀ ba sílẹ̀ pẹ̀lú ojú rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn Júdà àti Jérúsálẹ́mù wólẹ̀ níwájú láti sin Olúwa Nígbà náà díẹ̀ lára àwọn ọmọ Léfì àti àwọn ọmọ Kóhátì àti àwọn kórì sì dìde dúró wọ́n sì sin Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, pẹ̀lú ohùn ariwo ńlá Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù wọ́n jáde lọ sí ihà Tékòa Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń jáde lọ, Jéhóṣáfátì dìde dúró ó sì wí pé, Ẹgbọ́ mi, Júdà àti ènìyàn Jérúsálẹ́mù! Ẹ ní ìgbàgbọ́ ninú Olúwa Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì borí, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀ ẹ̀yìn yóò sì ṣe rere Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jéhóṣáfátì yàn wọ́n láti kọrin sí Olúwa àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí ìwájú ogun ńlá náà, wí pé Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa , nítorí àànú rẹ̀ dúró títí láéláé Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, Olúwa rán ogun ẹ́yìn sí àwọn ọkùnrín Ámónì àti Móábù àti òkè Séírì tí ó ń gbógun ti Júdà, wọ́n sì kọlù wọ́n Àwọn ọkùnrin Ámónì àti Móábu dìde dúró sí àwọn ọkùnrin tí ń gbé òkè Séírì láti pa wọ́n run túútúú Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti pa àwọn ọkùnrin làti òkè Séírì, wọ́n sì ran ra wọn lọ́wọ́ láti pa ara wọn run Nígbà tí Àwọn èníyàn Júdà jáde sí ìhà ilé ìsọ́ ní ihà, wọn ń wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, òkú nìkan ni wọ́n rí tí ó ṣubú sí ilẹ̀, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí àyè sá Bẹ́ẹ̀ ni Jéhóṣáfatì ati àwọn èniyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀ Ní ọjọ́ kẹ̀rin, wọn kó ara jọpọ̀ ní àfonífojì ìbùkún, níbi tí wọ́n ti ń fi ìbùkún fún Olúwa Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní àfonífojì ìbùkún títí di òní Nígbà náà wọ́n darí pẹ̀lú Jéhóṣáfátì, gbogbo àwọn ènìyan Júdà àti Jérúsálẹ́mù padà pẹ̀lú ayọ̀ sí Jérúsálẹ́mù, nítorí Olúwa ti fún wọn ní ìdí láti yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn Wọ́n sì wọ Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin àti dùùrù àti ipè Ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá si orí gbogbo ìjọba ilẹ̀ náà nígbà tí wọ́n gbọ́ bí Olúwa ti bá àwọn ọ̀ta Ísírẹ́lì jà Bẹ́ẹ̀ ni ìjọba Jéhóṣáfátì sì wà ní àlàáfíà, nítorí Ọlọ́run rẹ̀ ti fún-un ni ìsinmi ní gbogbo àyíká Báyìí ni Jéhóṣáfátì jọba lórí Júdà Ó sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì Nígbà tí ó di ọba Júdà, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ásúbà ọmọbìnrin Ṣílíhì Ó sì rin ọ̀nà baba rẹ̀ Ásà kò sì yà kúrò nínú rẹ̀, ó si ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Olúwa Ní ibi gíga, pẹ̀lúpẹ̀lù, kò mu wọn kúrò, gbogbo àwọn ènìyàn náà kò sì fi ọkan wọn fún Ọlọ́run àwọn baba wọn Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Jéhóṣáfátì, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sí inú ìwé ìtàn ti Jéhù ọmọ Hánánì, tí a kọ sí inú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì Nígbà tí ó yá, Jehóṣáfátì ọba Júdà da ara rẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú Áhásáyà, ọba Ísírẹ́lì, ẹni tí ó jẹ̀bi búburú ìwà Ó sì gbà pẹ̀lú rẹ̀ láti kan okọ̀ láti lọ sí Táríṣísì, lẹ́yìn èyí wọ́n kan ọkọ̀ ní Ésíonì-Gébérì Élísérì ọmọ Dáfídì ti Máréṣà sọtẹ́lẹ̀ sí Jóhóṣáfátì, wí pe, Nítorí tí ìwọ ti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Áhásáyà, Olúwa yóò pa ohun ti iwọ ti ṣe run Àwọn ọkọ̀ náà sì fọ́, wọn kò sì le lọ sí ibi ìtajà Jéhórámù Ọba Júdà Nígbà náà Jéhóṣáfátì sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dáfídì Jéhórámù ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Àwọn ará kùnrin Jéhóramù ọmọ Jéhóṣáfatì jẹ́ Áṣáríyà, Jèhíeli, Ṣekárià Ásáríyàhù, Míkáélí àti Ṣefátíá Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jéhóṣafátì ọba Ìsírẹlì Baba wọn ti fún wọn ní ẹ̀bun púpọ̀ ti fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò iyebíye pẹ̀lú àwọn ìlú ààbò ní Júdà, Ṣùgbọ́n, ó ti gbé ìjọba fún Jéhóramù nítori òun ni àkọ́bí ọmọkùnrin Nígbà tí Jéhórámù fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi lórí ìjọba baba a rẹ̀, ó pa gbogbo àwọn arákùrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìrin ọba Ìsirẹ́lì Jéhórámù jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjọ Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìdílé Áhábù ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ọmọbìrin Áhábù Ó ṣe búburú lójú Olúwa Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nítorí tí májẹ̀mú tí Olúwa ti dá fún Dáfídì kì í ṣe ífẹ́ Olúwa láti pa ìdílé Dáfídì run ó ti ṣe ìlérí láti tọ́jú fìtílà kan fún un àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ títí láé Ní àkókò Jéhórámù, Édómù ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà, wọ́n sì gbé ọba tiwọn kalẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni, Jéhórámù lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ Àwọn ará Édómù yí i ká àti àwọn alákóso àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n ó dìde ní òru ó sì sẹ́gun wọn ní òru Títí di ọjọ́ òní ni Édómù ti wà ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Júdà Líbínà ṣọ̀tẹ̀ ní àkọ́kọ́ náà, nítorí tí Jéhórámì ti kọ Olúwa sílẹ̀, Ọlọ́run àwọn baba a rẹ̀ Òun pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ibi gíga lórí àwọn òkè Júdà Ó sì ti fà á kí àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ó se àgbérè pẹ̀lú ara wọn Ó sì ti jẹ́ kí wọn ó ṣáko lọ Jóhórámì gba ìwé láti ọwọ́ Èlíjà wòlíì, tí ó wí pé Èyí ní ohun tí Olúwa , Ọlọ́run baba à rẹ Dáfídì wí Ìwọ kò tí ì rìn ní ọ̀nà àwọn baba à rẹ Jèhóṣáfátì tàbí Ásà ọba Júdà Ṣùgbọ́n ìwọ ti rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì, ìwọ sì ti tọ́ Júdà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì láti ṣe àgbèrè sí ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe Ìwọ sì ti pa àwọn arákùnrin rẹ, ẹ̀yà ara ilé bàbá à rẹ, àwọn ọkùnrin tí ó dára jù ọ́ lọ Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìn yìí, Ọlọ́run ti fẹ́rẹ́ lu àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìyàwó rẹ àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn ńlá Ìwọ tìkalára yóò ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú Àìsàn lílọ́ra ti ìfun, títí tí àìsàn náà yóò fi jẹ́ kí àwọn ìfun rẹ jáde sí ìta   Olúwa ru ìbínú àwọn, ará Fílístínì àti àwọn Árábù tí wọ́n ń gbé ní Ẹ̀bá àwọn ará Kúsì Wọ́n dojú ìjà kọ Júdà, wọ́n gbàá, wọ́n sì kó gbogbo ọrọ̀ tí a rí ní ilé ọba pẹ̀lú, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin kankan kò kù sílẹ̀ fún un bí kò ṣe Áhásáyà, tí ó kéré jùlọ Lẹ́yìn gbogbo èyí, Olúwa jẹ Jéhórámù níyà pẹ̀lú àrùn tí kò ṣeé wò sàn ti ìfun Ní àkókò kan ní ìparí ọdún kejì, àwọn ìfun rẹ̀ jáde nítorí àrùn náà ó sì kú nínu ìrora ńlá Àwọn Ènìyàn rẹ̀ kò dá iná láti fi bọlá fún un, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe fún àwọn baba a rẹ̀ Jéhórámù jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ní ìgbà tí ó di ọba, Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́jọ Ó kọjá lọ, kò sí ẹni tí ó kábàámọ̀ A sì sin ín si ìlú ńlá ti Dáfídì Ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú ibojì àwọn ọba Áhásáyà Ọba Júdà Àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù mú Áhásáyà, ọmọ Jéhórámù tí ó kéré jùlọ, jẹ ọba ní ipò rẹ̀, láti ìgbà tí àwọn onísùnmọ̀mí, tí ó wá pẹ̀lú àwọn ará Árábù sínú ibùdó, tí wọn sì ti pa àwọn ọmọkùnrin àgbà Bẹ́ẹ̀ ni Áhásáyà ọmọ Jéhórámù ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ sí ní Jọba Áhásáyà jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún kan Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Ataláyà, Ọmọ-ọmọbìnrin Ómírì Ó mú ìrìn ní ọ̀nà ilé Áhábù Nítorí tí ìyá rẹ̀ kì í láyà nínú ṣíṣe búburú Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa , gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe, Nítorí lẹ́yìn ikú bàbá a rẹ̀, wọ́n di olùgbani lámọ̀ràn rẹ̀ sí ṣíṣe rẹ̀ Ó tẹ̀lé ìgbìmọ̀ wọn nígbà tí ó lọ pẹ̀lú Jórámì ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì láti gbógun ti Háṣáélì ọba Árámì ní Rámótì Gílíádì Àwọn ará Árámì ṣá Jórámì lọ́gbẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí Jésírẹ́lì láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí wọ́n ti dá sí i lára ní Rámótì ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Háṣáélì ọba Árámì Nígbà náà, Áhásáyà, ọmọ Jehórámì ọba Júdà lọ sí Jésírẹ́lì láti lọ rí Jórámì ọmọ Áhábù nítorí a ti ṣáa lọ́gbẹ́ Ní gbogbo ìgbà ìbẹ̀wò Áhásáyà sí Jórámí, Ọlọ́run mú ìṣubú Áhásáyà wá Nígbà tí Áhásáyà dé, ó jáde lọ pẹ̀lú Jórámì láti lọ bá Jéhù ọmọ Nímísì, ẹni tí Olúwa ti fi àmì òróró yàn láti pa ìdílé Áhábù run Nígbà tí Jéhù ń ṣe ìdájọ́ lórí ilé Áhábù Ó rí ọmọbìrin ọba ti Júdà àti àwọn ọmọkùnrin ìbátan Áhásì Tí ó ń dásí Áhásáyà, ó sì pa wọ́n Ó lọ làti wá Áhásáyà, àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ Àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣẹ́gun rẹ̀ nígbà tí ó sá pamọ́ ní Saaríà A gbé e wá sí ọ̀dọ̀ Jéhù, a sì pa á Wọ́n sin ín nítorí wọ́n wí pé Ọmọkùnrin Jèhóṣáfátì ni, ẹni tí ó wá Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan ní ilé Áhásáyà tí ó lágbára láti gbé ìjọba náà dúró Nígbà tí Ataláyà ìyá Áhásáyà ríi wí pé ọmọkùnrin rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀ṣíwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba ti ilẹ̀ Júdà run Ṣùgbọ́n Jehóṣẹ́bà ọmọbìnrin ọba Jéhórámù mú Jóásì, ọmọkùnrin Áhásáyà ó sì jíi gbé lọ kúrò láàrin àwọn ọmọ-obìrin ọba, àwọn tí ó kù díẹ̀ kí wọn pa Wọn gbé òun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù Nítorí Jèhóṣebà ọmọbìnrin ọba Jehórámì àti ìyàwó àlùfáà Jéhóiádà jẹ́ arábìnrin Áhásáyà Ó fi ọmọ naà pamọ́ kúrò fún Ataláyà, kí ó má ba à pa á Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú wọn ni ilé Ọlọ́run fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataláyà ṣàkoso ilẹ̀ náà Ní ọdún kéje, Jehóádà fi agbára rẹ̀ hàn O dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn alákòóso, ọrọrún kan, Ásáríyà ọmọ Jérohámù, Íṣímáẹ́lì ọmọ Jehóhánániì Ásáríyà ọmọ Óbédì, Máséyà ọmọ Ádáyà àti Élíṣáfátì ọmọ Ṣkírì Wọ́n lọ sí gbogbo Júdà, wọ́n sì pe àwọn ará Léfì àti àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn ará Ísírẹ́lì láti gbogbo àwọn ìlú jọ Nígbà tí wọ́n wá sí Jérúsálẹ́mù Gbogbo ìpéjọ dá májẹ̀mú pẹ̀lú ọba ní ilé Ọlọ́run Jéhóiádà wí fún wọn pé, Ọmọkùnrin ọba yóò jọba, bí Olúwa ti ṣèlérí nípa àwọn àtẹ̀lé Dáfídì Nísinsinyìí èyí ni ohun tí ó yẹ kí ó ṣe Ìdámẹ́ta àlùfáà yín àti àwọn ará Léfì tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi ni kí ó bojútó àwọn ìlẹ̀kùn Ìdámẹ́ta yín níbi ààfin ọba àti ìdámẹ́ta níbi ẹnu odi ìdásílẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí ó wà ní àgbàlá ààfin ilé Olúwa Kò sí ẹnìkan tí ó gbọdọ̀ wọ inú ilé Olúwa yàtọ̀ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì tí a rán ní iṣẹ́ ìsìn Wọ́n lè wọlé nítori tí a ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí wọn ó ṣọ ohun tí Olúwa ti yàn fún wọn Àwọn ará Léfì gbọ́dọ̀ wà ní ìdúróṣinṣin yí ọba ká Olúkúlùkù pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ní ọwọ́ rẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé Olúwa ni kí ẹ pa Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tí ó bá lọ Àwọn ará Léfì àti gbogbo ọkùnrin Júdà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehóádà Àlùfáà ti palásẹ Olukúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀, àwọn tí wọ́n lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n ń kúrò ní ibi iṣẹ́ Nítorí Jéhóiádà àlùfáà kò ì tí tú ìpín kankan sílẹ̀ Nígbà náà, ó fún àwọn alákòóso ọrọrún ní ọkọ̀ àti ńlá àti kékeré apata, tí ó jẹ́ ti ọba Dáfídì tí wọn wà ní ilé Ọlọ́run Ó mú gbogbo àwọn ọkùnrin wà ní ipò ìdúró pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, yí ọba ká ní ẹ̀bá pẹpẹ àti ilé Olúwa láti ìhà gúsù sí ìhà àríwa ilé Olúwa Jéhóiádà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mú ọmọkùnrin ọba jáde wá wọ́n sì gbé adé sórí rẹ̀ Wọ́n mú ẹ̀dà májẹ̀mú kan fún un Wọ́n sì kéde rẹ̀ lọ́ba Wọ́n fi àmì òróró yàn án, wọ́n sì kígbe pé, Kí ọba kí ó pẹ́! Nígbà tí Ataláyà gbọ́ igbe àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sáré tí wọ́n ń kígbe ọba, ó lọ sí ọ̀dọ̀ wọn ní ilé Olúwa Ó sì wò, sì kíyèsì, ọba dúró ní ibùdúró rẹ̀ ní ẹ̀bá ẹnu-ọ̀nà, àti àwọn balógun àti àwọn afọ̀npè lọ́dọ̀ ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, wọ́n sì fọn ìpè, àti àwọn akọrin pẹ̀lú ohun èlò ìyìn, Nígbà náà ni Ataláyà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì kégbe wí pé, ọ̀tẹ̀! ọ̀tẹ̀! Jéhóiádà àlùfáà mú àwọn alákóso ọrọrún, tí ó wà ní àbojútó àwọn ọ̀wọ́ ogun, ó sì wá wí fún wọn pé Mú un jáde wá láàrin àwọn ọgbà, kí ẹ sì pa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀le Nítorí tí àlùfáà ti wí pé, Má se paá nínú ilé Olúwa Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ipá mú un kí ó tó dé ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ti ẹnu-òde ẹsin ní ìpìlẹ̀ ààfin Níbẹ̀ ni wọ́n sì ti pa á Jéhóiádà, nígbà náà dá májẹ̀mú pé òun àti àwọn ènìyàn àti ọba yóò jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run Gbogbo Àwọn ènìyàn lọ sí ilé Báálì, wọ́n sì fà á ya lulẹ̀ Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti àwọn òrìṣà, wọ́n sì pa Mátanì àlùfaà Báálì níwáju àwọn pẹpẹ Nígbà náà, Jéhóiádà tẹ àwòrán ilé Olúwa sí ọwọ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ará Leì ẹni tí Dáfídì ti fi ṣe iṣẹ́ ní ilé Olúwa láti tẹ ọrẹ sísun ti Olúwa bí a ti kọ ọ́ nínú òfin Mósè Pẹ̀lú ayọ̀ Àti orin kíkọ, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti pàsẹ Ó mú àwọn olùsọ́nà wà ni ipò ìdúró ní ẹnu odi ilé Olúwa kí ẹni aláìmọ́ nínú ohun-kóhun kó má baà wọlé Ó mú pẹ̀lú rẹ̀ àwọn alákóso ọrọrún, Àwọn eni-ọlá, àwọn olórí àwọn ènìyàn àti gbogbo àwọn Ènìyàn ilẹ̀ náà Ó sì mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé Olúwa Wọ́n lọ sínú Ààfin láti ẹnu òde tòkè Wọ́n sì fi ọba jókoó lórí ìtẹ́ Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì ń yọ̀ Ìlú naà sì dákẹ́ rọ́rọ́ Nítorí tí a pa Ataláyà pẹ̀lú idà Jóásì Tún Ilé Jóásì jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ogójì ọdún Orúkọ ìya rẹ̀ ni Ṣíbíà ti Béríṣébà Jóásì ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa ní gbogbo àkókò Jéhóiádà àlùfáà Jéhóiádà yan ìyàwó méjì fún-un, ó sì ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Ní àkókò kan, Jóásì pinnu láti tún ilé Olúwa ṣe Ó pe Àwọn Àlùfáà àti àwọn ará Léfì jọ, ó wí fún wọn pé, Ẹ lọ sí àwọn ìlú Júdà, kí ẹ sì gba owó ìtọ̀sì lati ọwọ́ gbogbo Ísírẹ́lì láti fi tún ilé Ọlọ́run ṣe, ṣé nísinsìn yìí Ṣùgbọ́n àwọn ará Léfì kò ṣe é lẹ́ẹ́kan naà Nítorí náà ọba paálásẹ fún Jéhóiádà olorí àlùfáà ó sì wí fún-un pé, Kí ni ó dé tí o kò, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ará Léfì láti mú wá láti Júdà àti Jérúsálẹ́mù, owó orí tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti fi lélẹ̀ àti nípasẹ̀ àpéjọ gbogbo Ísírẹ́lì fún àgọ́ ìjẹ́rìí Nísinsinyí, àwọn ọmọkùnrin, obìnrin búburú ni Ataláyà ti fọ́ ilé Ọlọ́run, ó sì ti lo àwọn nǹkan ìyàsọ́tọ̀ fún àwọn Báálì Nípasẹ̀ ọba, a ṣe àpótí wọ́n sì gbé e sí ìta, ní ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa A ṣe ìkéde ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù wí pé wọ́n gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa , owó orí tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti bèèrè lọ́wọ́ Ísírẹ́lì ní ihà Gbogbo àwọn ènìyàn mú gbogbo ìdá owó ti wọn wá pẹ̀lú ìdùnnú, wọ́n ń jù ú sínú àpótí títí tí ó fi kún Nígbà kígbà tí a bá gbé àpótí wọlé láti ọwọ́ àwọn ará Léfì sí ọwọ́ àwọn ìjòyè ọba, tí wọ́n bá sì rí wí pe owó ńlá wà níbẹ̀ àwọn akọ̀wé ọna àti ìjòyè olórí àlùfáà yóò wá láti kó owó rẹ̀ kúrò, wọn yóò sì dá a padà sí àyè rẹ̀ Wọ́n ṣe èyí déédéé, wọ́n sì kó iye owó ńlá Ọba àti Jéhóiádà fi fún àwọn ọkùnrin náà tí ó gbé iṣẹ́ náà jáde ti a bèrè fún ilé Olúwa Wọ́n fi owó gba ẹni tí ń fi òkúta mọ ilé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ilé Olúwa padà, àti àwọn òsìsẹ́ pẹ̀lú irin àti idẹ láti tún ilé Olúwa ṣe Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ náà, sì lọ ṣíwájú àti síwajú ní ọwọ́ wọn, wọ́n sì tún mú ilé Ọlọ́run dúró sí ipò rẹ̀, wọ́n mún un le Nígbà tí wọ́n sì parí rẹ̀ tán, wọ́n mú owó ìyókù wá sí iwájú ọba àti Jéhóíádà, a sì fi ohun èlò fún ilé Olúwa , àní ohun èlò fún ìsìn àti fún ẹbọ pẹ̀lú ọpọ́n, àni ohun èlò wúrà àti fàdákà Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé Olúwa nígbà gbogbo ní gbogbo ọjọ́ Jéhóiádà Ṣùgbọ́n Jéhóiádà di arúgbó, ó sì kún fún ọjọ́, ó sì kú, ẹni àádóje ọdún ni nígbà tí ó kú Wọ́n sì sin ín ní ìlú Dáfídì pẹ̀lú àwọn ọba, nítorí tí ó ṣe rere ní Ísírẹ́lì, àti sí Ọlọ́run àti sí ilé rẹ̀ Lẹ́yìn ikú Jéhóíadà, àwọn onisẹ́ Júdà wá láti fi ìforíbalẹ̀ wọn hàn sí ọba Ó sì fèsì sí wọn Wọ́n pa ilé Olúwa tì, Ọlọ́run baba a wọn Wọ́n sì ń sin àwọn òpó Áṣérà àti àwọn òrìṣà Nítorí ẹbí wọn, ìbínu Ọlọ́run dé sórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù Bí ó ti wù kí ó rí, Olúwa rán àwọn wòlíì sí àwọn ènìyàn láti mú wọn padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, wọ́n jẹ́rìí nípa wọn, wọn kì yóò gbọ́ Nígbà náà, ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Ṣákáríhà ọmọ Jéhóíádà wòlíì, ó dúró níwájú àwọn ènìyàn ó sì wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tẹ̀lé àṣẹ Olúwa Ìwọ kì yóò ṣe rere Nítorí tí ìwọ ti kọ Olúwa sílẹ̀, òun pẹ̀lú ti kọ̀ yín sílẹ̀   Ṣùgbọ́n wọ́n dìtẹ̀ sí i, àti nípa àṣẹ ọba, wọ́n sọ ọ́ lókúta pa nínú àgbàlá ààfin ilé Olúwa Ọba Jóáṣì kò rántí inú rere tí Jéhóiádà baba Ṣakaráyà ti fi hàn án ṣùgbọ́n, ó pa ọmọ rẹ̀, tí ó wí bí ó ti ń kú lọ pé, Kí Olúwa kí ó rí èyí kí ó sì pè ọ́ sí ìṣírò Ní òpin ọdún, àwọn ọmọ ogun Árámì yàn láti dojúkọ Jóáṣì wọ́n gbógun ti Júdà àti Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì pa gbogbo àwọn asáájú àwọn ènìyàn Wọ́n rán gbogbo àwọn ìkógun sí ọba wọn ní Dámásíkọ́sì Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ ogun Árámì ti wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀ Olúwa sì fi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí Júdà ti kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe ìdájọ́ Jóásì Nígbà tí àwọn ará Árámù kúrò, wọ́n fi Jóásì sílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọgbẹ́ Àwọn onísẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ si fún pípa ọmọ Jéhóiádà àlùfáà, wọ́n sì pa á ní orí ibùsùn rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, a sì sin ín sínú ìlú ńlá ti Dáfídì, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú àwọn ibojì àwọn ọba Àwọn tí ó dìtẹ̀ sì jẹ́ Ṣábádì, ọmọ Ṣíméátì arábìnrin Ámónì àti Jóhéṣábádì ọmọ Ṣímírítì arábìnrin Móábì Àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọ̀pọ̀ lọ́pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, àti àkọsílẹ̀ ti ìmúpadà sípò ilé Ọlọ́run ní a kọ sínú ìwe ìtumọ̀ ti àwọn ọba Ámásáyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ámásíà Ọba Júdà Ámásíà jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jéhóadánì, ó wá láti Jérúsálẹ́mù Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa , ṣùgbọ́n kì í ṣe tọkàntọkàn Lẹ́yìn tí ìjọba ti wà ní ìdarí rẹ̀, ó pa àwọn onísẹ́ tí ó pa baba rẹ̀ ọba Síbẹ̀ kò pa àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ nínú òfin nínú ìwé Mósè, níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé A kò gbọdọ̀ pa àwọn baba fún àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ fún baba wọn Olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ Ámásíà, pe gbogbo àwọn ènìyàn Júdà pọ̀, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn sí àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọrọrún fún gbogbo Júdà àti Bẹńjámínì, ó sì gbá iye wọn láti ẹni ogún ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ, ó sì ríi pé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dógún àwọn ọkùnrin ni ó ti múra fún ìsìn ogun, tí ó lè gbá ọ̀kọ̀ àti àpáta mú Ó sì yá ọ̀kẹ́ márùn-ún àwọn ọkùnrin oníjà láti Ísírẹ́lì fún ọgọ́rùn-ún mẹ́wàá àwọn talẹ́ntì fàdákà Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ ọ́ wá ó sì wí pé, Ọba, àwọn ọ̀wọ́-ogun láti Ísírẹ́lì kò gbọdọ̀ yan pẹ̀lú rẹ, nítorí tí Olúwa kò wà pẹ̀lú Ísírẹ́lì kì í ṣe pẹ̀lú ẹnìkankan láti Éfíráímù Àní, tí ẹ bá lọ jà pẹ̀lú ìmúláyàle ní ojú ogun, Ọlọ́run yóò bì ọ́ subú níwájú àwọn ọ̀tá, nítorí Olúwa ní agbára láti ràn ọ́ lọ́wọ́ àti láti bì ọ́ ṣubú Ámásíà sì bi ènìyàn Ọlọ́run pé, Ọgọ́rùnún tálẹ́ntì tí mo ti san fún àwọn ọ̀wọ́-ogun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kọ́ Ènìyàn Ọlọ́run dáhùn pé Olúwa lè fún ọ ní èyí tí ó ju ìyẹn lọ Bẹ́ẹ̀ ni Ámásíà, tú àwọn ọwọ́ ogun tí ó ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Éfíráimù ká Ó sì rán wọn lọ lé Wọ́n kún fún ìbínú pẹ̀lú Júdà, wọ́n sì padà lọlé pẹ̀lu ìbínú ńlá Ámásíà nígbà náà, tó agbára rẹ̀ ó sì fọ̀nàhan àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, iyọ̀, níbi tí ó ti pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn ọkùnrin Séírì Àwọn ọkùnrin Júdà pẹ̀lú fi agbára mú àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́wá láàyè Wọ́n mú wọn lọ sí orí òkè bèbè òkúta, wọ́n jù wọ́n sílẹ̀, kí gbogbo wọn sì fọ́ sí wẹ́wẹ́ Ní báyìí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí Ámásíà ti rán lọ padà, tí wọn kò nípa nínú ogun gbógun sí àwọn ìlú Júdà láti Saaríà sí Bẹti-Hórónì Wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ìkógun ńlá Nígbà tí Ámásíà padà ní ibi pípa àwọn ará Édómù, ó mú àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn Séírì padà wá Ó gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àwọn Ọlọ́run tirẹ̀ Ó tẹríba fún wọn, ó sì rúbọ fún wọn Ìbínú Olúwa ru sí Ámásíà, ó sì rán wòlíì kan sí i, tí ó wí pé, kí ni ó dé tí ìwọ fi ń bèrè lọ́wọ́ àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn yìí, tí wọn kò le gba àwọn ènìyàn ti wọn kúrò lọ́wọ́ rẹ Bí ó ti n sọ̀rọ̀, ọba wí fún un pé, Ṣé a yàn ọ́ ní olùgbà ọba lámọ̀ràn ni Dúró! Èéṣe tí a ó fi lù ọ́ bolẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni, wòlíì náà dúró ṣùgbọ́n ó wí pé, Èmi mọ̀ pé Olúwa ti pinnu láti pa ọ́ run nítorí ìwọ ti ṣe èyí, ìwọ kò sì tẹ́tísí ìmọ̀ràn mi Lẹ́yìn tí Ámásíà ọba Júdà ti bèèrè lọ́wọ́ àwọn olùgbà á lámọ̀ràn, ó rán ìpèníjà yìí sí Jehóáṣì ọmọ Jehóáháṣì ọmọ Jéhù, ọba Ísírẹ́lì pé Wá bá mi lóju kojú Ṣùgbọ́n Jéhóáṣì ọba Ísírẹ́lì fèsì padà sí Ámásíà ọba Júdà pé, Òṣùṣù kan ní Lẹ́bánónì rán isẹ́ sí òpépé ní Lẹ́bánónì, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwo Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lébánónì wá, ó sì tẹ òṣùṣù náà lábẹ́ ẹsẹ̀ Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Édómù àti nísinsin yìí ìwọ ní ìrera àti ìgbéraga Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí o fi n wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Júdà pẹ̀lu Ámásíà, bí ó tì wù kí ó rí kò ní tẹ́tí nítorí Ọlọ́run ṣe é kí ó lè gbé wọn lé Jéhóásì lọ́wọ́ nítorí wọ́n wá àwọn ọlọ́run Édómù Bẹ́ẹ̀ ni Jóásì, ọba Ísírẹ́lì òun àti Ámásíà ọba Júdà dojúkọ ara wọn ní Bẹti Ṣeméṣì ní Júdà Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì da Júdà rú, gbogbo olúkúlùkù ènìyàn sì sálọ sí ìlú rẹ̀ Jóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Áhásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóáṣì ọmọ Áhásáyà ní Bétì Ṣéméṣì Nígbà náà Jóásì mú u wá sí Jérúsálẹ́mù Ó sì wó ògiri Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ẹnu ọ̀nà Éfíráímù sí igun ẹnu ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí ọgọ́rùnún mẹ́fà ẹsẹ̀ bàtà ní gígùn Ó kó gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò tí wọ́n rí ni ile Ọlọ́run tí ọ́ wà ní àbojútó Obedi Édómù, lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣura ààfin àti àwọn ìdógó, ó sì padà sí Saaríà Ámásíà ọmọ Jóáṣì ọba Júdà gbé fún ọdun mẹ́ẹ̀dógún lẹ́yìn ikú Jehóaṣì ọmọ Jehóáháṣì ọba Ísírẹ́lì Fún ti iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Ámásíà láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé àwọn ọba Júdà àti Ísírẹ́lì Láti ìgbà tí Ámásíà ti yípadà kúrò láti máa tẹ̀lé Olúwa , wọ́n dìtẹ̀ síi ní Jérúsálẹ́mù, ó sì sálọ sí Lákíṣì ṣùgbọ́n, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e lọ sí Lákiṣì, wọ́n sì paá síbẹ̀ A gbé e padà pẹ̀lú ẹsin A sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Júdà Ùsáyà Ọba Júdà Nígbà náà gbogbo ènìyàn Júdà mú Ùsáyà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún wọ́n sì fi jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ Ámásíà Òun ni ẹni náà tí ó tún Élótù kọ́, ó sì mú padà sí Júdà Lẹ́yìn ìgbà tí Ámásíà ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ Ùsáyà sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìléláadọ́ta Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekolíà ó sì wá láti Jérúsálẹ́mù Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa , gẹ́gẹ́ bi baba rẹ̀ Ámásíà ti ṣe Ó sì wá Olúwa ní ọjọ́ Sekaríà, ẹni tí ó ní òye nínú ìran Ọlọ́run Níwọ̀n ọjọ́ tí ó wá ojú Olúwa , Ọlọ́run fún-un ní ohun rere Ó sì lọ sí ogun lórí Fílístínì ó sì wó odi Gátì lulẹ̀, Jábìnè àti Ásídódù Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Ásídódù àti níbì kan láàrin àwọn ará Fílístínì Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lóri àwọn ará Fílístínì àti Árábù tí ń gbé ní Gúrì Bálì àti lórí àwọn ará Méhúmì Àwọn ará Ámórì gbé ẹ̀bùn wá fún Usíà, orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ Éjíbítì, nítorí ó ti di alágbára ńlá Ùsáyà sì kọ́ ìlú sí Jérúsálẹ́mù níbi ẹnu bodè igun, àti nibi ẹnu bodè àfonífojì àti nibi ìṣẹ́po-odi ó sì mú wọn le Ó sì tún ilé ìṣọ́ ihà kọ́, ó sì gbẹ́ kàǹga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbààjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe Úsíà sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Jégíélì akọ̀wé àti Máséía ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ Hánánì, ọ̀kan lára àwọn olórí ogun Àpapọ̀ iye olórí àwọn baba lórí àwọn alágbára akọni ogun jẹ́ ẹgbẹ̀ta Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dogún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárún , tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀ Ùsáyà sì pèsè ọ̀kọ̀, asà, akọ́rọ́, àti ohun èlò ìhámọ́ra ọrun títí dé òkúta kànnàkànnà fún ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Ní Jérúsálẹ́mù ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun tí ó ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ihumọ̀ ọlọgbọ́n ọkùnrin fún lílò lórí ilé-ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí Ùsáyà jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú Ó sì di aláìsòótọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ Ó sì wo ilé Olúwa láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí Ásáríyà àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọgọ́rin alágbára àlùfáà Olúwa mìíràn sì tẹ̀lée Wọ́n sì takòó, wọn sì wí pé, Kò dára fún ọ, Ùsáyà, láti sun tùràrí sí Olúwa Èyi fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Árónì, ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìsòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Ùsía, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣe tán láti sun tùràrí, ó sì bínú Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé Olúwa , ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀ Nígbà tí Ásáríyà olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn àlùfáà yòókù sì wò ó, wọ́n sì ríi wí pé ó ní ẹ̀tẹ̀ níwájú orí rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì sáré gbé e jáde pẹ̀lú pẹ̀lú, òun tìkálárarẹ̀ ti fẹ́ láti jáde, nítorí tí Olúwa ti lùú Ọba Ùsíá sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀ Ó sì gbé ní ilé ọ̀tọ̀ adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ile Olúwa Jótamù ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Ùsía láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ láti ọwọ́ wòlíì Ìsàíà ọmọ Ámósì Ùsáyà sì sùn pẹ̀lú àwọn baba, rẹ̀ a sì sin sí ẹ̀gbẹ́ wọn nínú oko ìsìnkú fún ti iṣẹ́ tí àwọn ọba, nítorí àwọn ènìyàn wí pé ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, Jótamù ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀ Jótámù Ọba Júdà Jótámù sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì di ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógun Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jérúsà ọmọbìnrin Sádókì Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa , gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ùsáyà ti ṣe, ṣùgbọ́n kìkì wí pé kò wọ ilé Olúwa Àwọn ènìyàn síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń se iṣẹ́ ibi wọn Jótanì sì kọ́ ẹnu ọ̀nà gíga ilé Olúwa ó sì ṣe iṣẹ́ lórí odi ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Óféli Ó sì kọ́ àwọn ìlú ní Júdà òkè àti nínú igbó àti ilé ìsọ́, ó mọ ilé odi Jótanì sì ṣẹ́ ogun lórí ọba àwọn ará Ámónì ó sì borí wọn Ní ọdún náà àwọn ará Ámórì wọ́n sì san fún ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì fàdákà àti ẹgbàaàrún òsùwọ̀n àlìkámà àti ẹgbàárún balì Àwọn ará Ámónì gbé e wá ní iye kan náà àti pẹ̀lú ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta Jótamù sì di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà tótọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Jótamù, pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀ pẹ̀lú ohun mìíràn tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà Ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógún Jótamù sì sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Dáfídì, Áhásì ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀ Áhásì ọba Júdà Áhásì sì jẹ́ ẹni ogún ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógún Gẹ́gẹ́ bí i Dáfídì bàbá rẹ̀ kò sì ṣe ohun rere ní ojú Olúwa Ó sì rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì ó sì ṣe ere dídá fún ìsìn Báálì Ó sì sun ẹbọ ní àfonífojì Hínómù, ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní ibi gíga wọ̀n nì lóri òkè kékeré àti lábẹ́ gbogbo igi tútù Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fi lé ọba Síríà lọ́wọ́ Àwọn ará Síríà sì pa á run, wọ́n sì kó púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn wá sí Dámásíkù Ó sì tún fi lé ọwọ́ ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú, ẹni tí ó kó wọn ní ìgbékùn púpọ̀ tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa Ní ọjọ́ kan Pékà, ọmọ Remalíà, pa ọ̀kẹ́ mẹ́fà àwọn ọmọ ogun ní Júdà nítorí Júdà ti kọ Olúwa Ọlọ́run bàbá wọn sílẹ̀ Síkíiì àti Éfúráímù alágbára sì pa Máséíẹ̀ ọmọ ọba, Ásíríkámù ìjòyè tí ó wà ní ìkáwọ́ ilé ọba, àti Elikánà igbákejì ọba Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kó ní ìgbékùn lára àwọn arákùnrin wọn ọ̀kẹ́ mẹ́wàá àwọn aya wọn, àwọn ọmọkùnrin àti obìnrin wọn sì tún kó ọ̀pọ̀ ìkógun, èyí tí wọn kó padà lọ sí Saáríà Ṣùgbọ́n wòlíì Olúwa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ódédì wà níbẹ̀, ó sì jáde lọ láti lọ pàdé ogun nígbà tí ó padà sí Saáríà Ó sì wí fún wọn pé, Nítorí Olúwa , Ọlọ́run Baba yín bínú sí Júdà ó sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin pa wọ́n ní ìpa oró tí ó de òkè ọ̀run Nísinsinyìí ẹ̀yin ń pète láti mú ọkùnrin àti obìnrin Júdà àti Jerúsálémù ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú yín, ẹ̀yin kò há jẹ̀bi Olúwa Ọlọ́run yín, àní ẹ̀yin Nísinsinyìí ẹ gbọ́ tèmi! Ẹ rán àwọn ìgbékùn tí ẹ̀yin ti mú gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹwọ̀n padà nítorí ìbínú kíkan Olúwa ńbẹ lórí yín Lẹ́yìn náà, díẹ̀ nínú àwọn olórí ní Éfùráímù Ásáríyà ọmọ Jehóhánánì, Béríkià ọmọ Méṣílemóti, Jehísikíà ọmọ Ṣaílúmù, àti Ámásà ọmọ Hádíà, dìde sí àwọn tí o ti ogun náà bọ̀ Ìwọ kò gbọdọ̀ mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá síbí, wọ́n wí pé, tàbí àwa ti jẹ̀bi níwájú Olúwa , ṣe ẹ̀yin ń gbèrò láti fi kún ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀bi wa ni nítorí tí ẹ̀bi wa ti tóbi pupọ̀, ìbínú rẹ̀ kíkan sì wà lórí Ísírẹ́lì Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ológun tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ìkógún sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè àti gbogbo ìjọ ènìyàn Àwọn ọkùnrin tí a pè pẹ̀lu orúkọ náà sì dìde, wọn sì mú àwọn ìgbékùn náà, wọ́n sì fi ìkógun náà wọ̀ gbogbo àwọn tí ó wà ní ìhòǹhò nínú wọn, wọ́n sì wọ̀ wọ́n ní aṣọ, wọ́n sì bọ̀ wọ́n ní bàtà, wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ àti ohun mímu, wọ́n sì fi òróró kùn wọ́n ní ara, wọ́n sì kó gbogbo àwọ̀n tí ó jẹ́ aláìlera nínú wọ́n sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kó wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Jẹ́ríkò, ìlú ọlọ́pẹ, wọ́n sì padà sí Samaríà Ní àkókò ìgbà náà, ọba Áhásì ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà fún ìrànlọ́wọ́ Àwọn ará Édómù sì tún padà wá láti kọlu Júdà kí wọn sì kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ Nígbà tí àwọn ará Fílístínì sì ti jagun ní ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n nì àti síhà gúsù Júdà Wọ́n sẹ́gun wọ́n sì gba Béti-ṣémésì, Áíjálónì àti Gédérótì, àti Sókò, Tímínà, a ri Gímísò, pẹ̀lú ìletò wọn Olúwa sì rẹ Júdà sílẹ̀ nítorí Áhásì ọba Ísírẹ́lì, nítorí ó sọ Júdà di aláìní ìrànlọ́wọ́, ó sì se ìrékọjá gidigidi sí Olúwa Tílgátì-Pílésárì ọba Ásíríà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́ Áhásì mú díẹ̀ nínú ìní ilé Olúwa àti láti ilé ọba àti láti ọ̀dọ̀ ọba ó sì fi wọ́n fún ọba Ásíríà ṣùgbọ́n èyí kò ràn wọ́n lọ́wọ́ Ní àkókò ìpọ́njú rẹ̀ ọba Áhásì sì di aláìsòótọ́ sí Olúwa Ó sì rú ẹbọ sí òrìṣà àwọn Dámásíkù, ẹni tí ó sẹ́gun wọn, nítorí ó rò wí pé, Nítorí àwọn òrìṣà àwọn síríà ti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọn kí ó bà lè ràn mí lọ́wọ́ Ṣùgbọ́n àwọn ni ìparun rẹ̀ àti ti gbogbo Ísírẹ́lì Áhásì sì kó jọ gbogbo ohun èlò lati ilé Olúwa jọ ó sì kó wọn lọ Ó sì ti ilẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tẹ́ pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun Jérúsálẹ́mù Ní gbogbo ìlú Júdà ó sì kọ́ ibi gíga láti sun ẹbọ fún àwọn Ọlọ́run mìíràn Kí ó sì mú Olúwa , Ọlọ́run àwọn Baba wọn bínú Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì Áhásì sì sùn pẹ̀lú àwọn Baba rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Jérúsálẹ́mù ṣùgbọ́n wọn kò mú un wá sínú àwọn ìsà òkú àwọn ọba Ísírẹ́lì Heṣekáyà ọmọ rẹ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀ Hesekíáyà Sọ Ilé Heṣekáyà sì jẹ́ ẹni ọdún mẹẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ábíjà ọmọbìnrin Sékáríà Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa , gẹ́gẹ́ bí bàba rẹ̀ Dáfídì ti ṣe Ní osù àkọ́kọ́ ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, ó sì sí àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tún wọn ṣe Ó sì mú àwọn àlùfáà wá àti àwọn ọmọ Léfì, ó sì kó wọn jọ yíká ìta ìlà òorùn Ó sì wí pé, Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin ọmọ Léfì! Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nísinsin yìí kí ẹ sì ya ile Olúwa Ọlọ́run sí mímọ́, kí ẹ sì kó ohun àìmọ́ bàbá jáde kúrò ní ibi mímọ́ Àwọn baba wa jẹ́ aláìsòótọ́ wọ́n sì ṣe ohun àìtọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Wọ́n sì yí ojú wọn padà kúrò ní ibùgbé Olúwa , wọ́n sì pa ẹ̀yìn wọn dà sí i Wọ́n sì tún ti ìlẹ̀kùn ìloro náà pẹ̀lú, wọ́n sì pa Fìtílà Wọn kò sì sun tùràrí tàbí pèsè ẹbọ sísun si ibi mímọ́ si Ọlọ́run Ísirẹ́lì Nítorí náà, ìbínú Olúwa ti ru sókè wá sórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù ó sì ti fi wọ́n ṣe ohun èlò fún wàhálà, àti ìyanu àti ẹ̀sín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fi ojú rẹ̀ rí i Ìdí nìyí tí àwọn bàbá wa ṣe ṣubú nípa idà àti idí tí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àti àwọn aya wa ti wọn kó wọ́n ní ìgbékùn Nísinsìn yìí ó wà ní ọkàn mi láti bá Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú Bẹ́ẹ̀ ni kí ìbínú rẹ̀ kíkan kí ó lè yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa Àwọn ọmọ mi, ẹ má ṣe jáfara nísinsìn yìí, nítorí tí Olúwa ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀ láti sin, kí ẹ sì máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti sun tùràrí Nígbà náà àwọn ọmọ Léfì wọ̀nyí múra láti ṣe iṣẹ́ nínú àwọn ọmọ Kóhátì, Máhátì ọmọ Ámásà àti jóẹ́lì ọmọ Ásáríyà nínú àwọn ọmọ Mérárì, Kíṣì ọmọ Ábídì àti Ásáríyà ọmọ Jéháiéíèlì nínú àwọn ọmọ Gésónì, Jóà, ọmọ símà àti Édẹ́nì ọmọ Jóà nínú àwọn ọmọ Élisáfánì, Ṣímírì àti Jégíèlì nínú àwọn ọmọ Ásáfù, Sékáríà àti Mátaníyà nínú àwọn ọmọ Hémánì, Jéhíélì àti Ṣíméhì nínú àwọn ọmọ Jédútùnì, Ṣémáíà àti Húsíélì Nigbà tí wọ́n sì ti kó ara wọn jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì lọ láti gbá ile Olúwa mọ́, gẹ́gẹ́ bí ọba ti paáláṣẹ, ẹ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Olúwa Àwọn àlùfaà sì wọ inú ilé Olúwa lọ́hùn ún lọ láti gbá a mọ́ Wọ́n sì gbé e jáde sí inú àgbàlá ilé Olúwa gbogbo ohun àìmọ́ tí wọ́n rí nínú ilé Olúwa Àwọn ọmọ Léfì sì mú u wọ́n sì gbé e jáde sí gbangba odò Kédírónì Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìyà sí mímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní osù kìn-ín-ní, àti ní ọjọ́ kẹjọ oṣù náà wọ́n sì dé ìloro Olúwa Fún ọjọ́ mẹ́jọ mìíràn síi, wọ́n sì ya ilé Olúwa sí mímọ́ fún rarẹ̀ Wọ́n sì parí ní ọjọ́ kẹ́rìndínlógún oṣù kìn-ín-ní Nígbà náà wọn sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Héṣékíà láti lọ jábọ̀ fún un Àwa ti gbá ilé Olúwa mọ́, pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú gbogbo ohun ẹbọ rẹ̀, àti tábìlì àkàrà ìfihàn, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò A ti pèsè àsì ti yà sí mímọ́ gbogbo ohun èlò tí ọba Áhásì ti sọ di aláìmọ́ nínú àìsòótọ́ rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọba nísinsìn yìí, wọ́n wà níwájú pẹpẹ Olúwa Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọba Hésékíà sì kó olórí àwọn ìjòyè jọ, ó sì lọ sókè ilé Olúwa Wọ́n sì mú akọ màlúù méje wá, àti àgbò méje, àti ọ̀dọ́ àgùntàn méje àti òbúkọ méje gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba, fún ibi mímọ́ àti fún Júdà Ọba pàsẹ fun àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Árónì, láti se èyí lórí pẹpẹ Olúwa Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pa akọ màlúù, àwọn àlùfáà mú ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n sì fi wọ́n ara pẹpẹ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni nígbà tí wọ́n pa àgbò, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n orí pẹpẹ Nígbà náà wọ́n sì pa ọ̀dọ́ àgùntàn, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn ara pẹpẹ Òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n gbé wá síwájú ọba àti ìjọ ènìyàn, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn Àwọn àlùfáà wọn sì pa Òbúkọ, wọ́n sì gbé ẹ̀jẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún gbogbo Ísírẹ́lì, nítorí ọba ti pàsẹ kí a ṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹṣẹ fún gbogbo Íṣírẹ́lì Ó sì mú àwọn Léfì dúró nínú ilé Olúwa pẹ̀lú Kíḿbálì ohun èlò orin àti dùùrù ní ọ̀nà tí a ti palásẹ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Dáfídì àti Gádì aríran ọba àti Nátanì wòlíì Èyí ni a pa lásẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa láti ọwọ́ àwọn wòlíì rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì sì dúró pẹ̀lú ohun èlò orin Dáfídì, àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ipè wọn Hésékíà sì pa á láṣẹ láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ, bí ẹbọ sísun náà ti bẹ̀rẹ̀, orin sí Olúwa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú ohun èlò orin Dáfídì ọba Ísírẹ́lì Gbogbo ìjọ ènìyàn náà sì wólẹ̀ sìn, àwọn akọrin kọrin, àwọn afọ̀npè sì fọn ìpè gbogbo wọ̀nyí sì wà bẹ́ẹ̀ títí ẹbọ sísun náà fi parí tán Nígbà tí wọ́n sì ṣe ìparí ẹbo rírú, ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ ara wọn ba, wọ́n sì sìn Pẹ̀lúpẹ́lú Heṣekáyà ọba, àti àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì, láti fi ọ̀rọ̀ Dáfídì àti ti Ásáfù aríran, kọrin ìyìn sí Olúwa wọ́n sì fi inú dídùn kọrin ìyìn, wọ́n sì tẹrí wọn ba, wọ́n sì sìn Nígbà náà ni Hesekíáyà dáhùn, ó sì wí pé, nísinsin yìí, ọwọ́ yín kún fún ẹ̀bùn fún Olúwa , ẹ súnmọ ìhín, kí ẹ sì mú ẹbọ àti ọrẹ ọpẹ́ wá sínú ilé Olúwa Ìjọ ènìyàn sì mú ẹbọ àti ọrẹ-ọpẹ́ wá àti olúkúlùkù tí ọkàn rẹ̀ fẹ́, mú ẹbọ sísun wá Iye ẹbọ sísun, tí ìjọ ènìyàn mú wá, sì jẹ́ àádọ́rin akọ màlúù, àti ọgọ́rùnún àgbò, àti igba ọ̀dọ́-àgùntàn gbogbo wọ̀nyí sì ni fún ẹbọ ṣíṣun sí Olúwa Àwọn ohun ìyà sí mímọ́ sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta màlúù, àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún àgùntàn Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà kò pọ̀ tó, wọn kò sì le bó gbogbo àwọn ẹran ẹbọ sísun náà nítorí náà àwọn arákùnrin wọn, àwọn Lefi ràn wọ́n lọ́wọ́, títí iṣe náà fi parí, àti títí àwọn àlùfáà ìyókù fi yà wọ́n sí mímọ́ nítorí àwọn ọmọ Léfì ṣe olóòtọ́ ní ọkàn ju àwọn àlùfáà lọ láti ya ara wọn sí mímọ́ Àti pẹ̀lú, àwọn ẹbọ sísun pàpọ̀jù, pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, pẹ̀lú ẹbọ ohun-mímu fún ẹbọ sísun Bẹ́ẹ̀ ni a sì tún dá ti iṣẹ́-ìsìn ilé Olúwa sílẹ̀ Heṣekáyà sì yọ̀, àti gbogbo ènìyàn pé, Ọlọ́run ti múra àwọn ènìyàn náà sílẹ̀, nítorí lójijì ni a ṣe nǹkan náà Sólómónì Kọ́ Ilé Nígbà náà, Sólómónì bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù lórí òkè Móríà, níbi tí Olúwa ti farahan bàbá a rẹ̀ Dáfídì Ní ori ilẹ̀ ìpakà Áráúnà ará Jébúsì, ibi tí Dáfídì pèsè Ó bẹ̀rẹ̀ sí kíkọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù kejì ní ọdún kẹ́rin ìjọba rẹ̀ Ìpìlẹ̀ tí Sólómónì gbé kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́ta gígùn ìgbọ̀nwọ́ àti ogún fífẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ Ìloro tí ó wà níwájú ilé Olúwa náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ Ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú kìkì wúrà Ó fi igi fírì bo ilé yàrá ńlá náà ó sì bòó pẹ̀lú kìkì wúrà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú igi ọ̀pẹ àti àwòrán ẹ̀wọ̀n Ó se ilé Olúwa náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òkúta iyebíye Góòlù tí ó lò jẹ́ wúrà párifáímù Ó tẹ́ àjà ilé náà pẹ̀lú ìtí igi àti ìlẹ̀kùn ògiri àti àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa Pẹ̀lú wúrà, ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù sára ògiri Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé Olúwa mu, ogún ìgbọ̀nwọ́ fún gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú ọgọ́rin mẹ́fà talẹ́ntì ti wúrà dáradára Ìwọn àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta Ṣékélì Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà Ní ibi mímọ́ jùlọ, ógbẹ́ àwòrán igi kérúbù kan, ó sì tẹ́ wọn pẹ̀lú wúrà Iye ìyẹ́ apá ìbú atẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa Nígbà tí ìyẹ́ apa kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-un ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn Ní ìjọra, ìyẹ́ apá kan ní ti kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa mìíràn ìyẹ́ apá rẹ̀ mìíràn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ní gígùn pẹ̀lú Tí ó farakan ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́ Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù wọ̀nyìí gbà tó ogún ìgbọ̀nwọ́ Wọ́n dúró ní ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí yàrá pàtàkì ńlá naà Ó ṣe aṣọ títa ní àwọ̀ ojú ọ̀run, àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ pẹ̀lú kérúbù tí a se sórí i rẹ̀ Níwájú ilé Olúwa náà ó ṣe òpó méjì tí lápapọ̀ jẹ́ márùn ún dín lógójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, olúkúlùkù pẹ̀lú olórí lórí rẹ̀ tí o ń wọn ìgbọ̀nwọ́ márùn ún Ó ṣe ẹ̀wọ̀n tí a hun wọ inú ara wọn, ó gbé wọn ká orí òpó náà Ó ṣe ọgọ́rin Pomígíránátìo ó sì so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé Olúwa , ọ̀kan sí gúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá Èyí ti gúsù, ó ṣe ní Jákínì àti èyí ti àríwá, ó ṣe ní Bóásì Heṣekáyà Se Àsè Ìrékọjá Hésékíà sì ránsẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà, ó sì kọ ìwé sí Éfúráímù àti Mánásè, kí wọn kí ó wá sínú ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì Nítorí tí ọba ti gbìmọ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo ìjọ ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù, láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní oṣù kejì Nítorí wọn kò lè pa á mọ́ ní àkókò náà, nítorí àwọn àlùfáà kò tí i ya ara wọn sí mímọ́ tó bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò tí ì kó ara wọn jọ sí Jérúsálẹ́mù Ọ̀ràn náà sí tọ́ lójú ọba àti lójú gbogbo ìjọ ènìyàn Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Ísírẹ́lì láti Beerí-sébà àní títí dé Dánì, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní Jérúsálẹ́mù nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ Bẹ́ẹ̀ àwọn oníṣẹ tí ń sáré lọ pẹ̀lú ìwé láti ọwọ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, wí pé Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì ẹ yí padà sí Olúwa Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísáákì, àti Ísírẹ́lì, òun ó sì yípadà sí àwọn ìyókù nínú yín, tí ó sálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba Ásíríà Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe dàbí àwọn baba yín, àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó dẹ́sẹ̀ sí Olúwa , Ọlọ́run àwọn baba wọn, nítorí náà ní ó ṣe fi wọ́n fún ìdahoro bí ẹ̀yin ti rí Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin kí ó má se ṣe ọlọ́rùn líle, bí àwọn baba yín, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín lọ́wọ́ fún Olúwa , kí ẹ sì wọ inú ibi mímọ́ rẹ̀ lọ, ti òun ti ìyà sí mímọ́ títí láé Kí ẹ sì sin Olúwa , Ọlọ́run yín kí ìmúná ìbínú rẹ̀ kí ó lè yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín Nítorí bí ẹ̀yin bá tún yípadà sí Olúwa , àwọn arákùnrin yín, àti àwọn ọmọ yín, yóò rí àánú níwájú àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, kí wọn kí ó lè tún padà wá sí ilẹ̀ yí nítorí Olúwa Ọlọ́run yín, oníyọ́nú àti aláàánú ni, kì yóò sì yí ojú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ yín, bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn onísẹ́ náà kọjá lati ìlú dé ìlú, ní ilẹ̀ Éfúráímù àti Mánásè títí dé Sébúlúnì Ṣùgbọ́n wọ́n fi wọ́n rẹ́rín ẹlẹ́yà, wọ́n sì gàn wọ́n Síbẹ̀ òmíràn nínú àwọn ènìyàn Áṣérì àti Mánásè àti Sébúlúnì rẹ̀ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Jérúsálẹ́mù Ní Júdà pẹ̀lú, ọwọ́ Ọlọ́run wá láti fún wọn ní ọkàn kan láti pa òfin ọba mọ́ àti tí àwọn ìjòyè, nípa ọ̀rọ̀ Olúwa Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì péjọ ní Jérúsálẹ́mù, láti pa àjọ àkàrà aláìwú mọ́ ní oṣù kejì Wọ́n sì dìde, wọ́n sì kó gbogbo pẹpẹ tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù lọ, àti gbogbo pẹpẹ tùràrí ni wọ́n kó lọ, wọ́n sì dà wọ́n sí odò Kídírónì Nígbà náà ni wọ́n pa ẹran ìrékọjá náà ní ọjọ́ kẹ́rinlà oṣù kejì ojú sì ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì yà ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sínú ilé Olúwa Wọ́n sì dúró ní ipò wọn, bí ètò wọn gẹ́gẹ́ bí òfin Mósè, ènìyàn Ọlọ́run àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà, tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Léfì Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ ènìyàn náà tí kò yà ara wọn sí mímọ́ wọn pa ẹran ìrékọjá fún olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe aláìmọ́, láti yà á sí mímọ́ sí Olúwa Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àni ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Éfíráimù àti Mánásè, Ísákárì, àti Sébúlúnì kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá naà, kì íṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ Ṣùgbọ́n Heṣekáyà bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, Olúwa , ẹni rere, dáríjin olúkúlùkù, Tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì íṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́ Olúwa sì gbọ́ ti Hesékíà, ó sì mú àwọn ènìyàn náà lára dá Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a rí ní Jérúsálẹ́mù fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà aláìwú mọ́ ní ọjọ́ méje àwọn ọmọ Léfì, àti àwọn àlùfáà yin Olúwa lójojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí Olúwa Heṣekáyà sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Léfì, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere Olúwa ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àṣè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún Olúwa , Ọlọ́run àwọn baba wọn Gbogbo ìjọ náà sì gbìmọ̀ láti pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́ wọ́n sì fi ayọ̀ pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́ Nítorí Heṣekáyà, ọba Júdà, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárún àgùntàn Ọ̀pọlọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́ Gbogbo ìjọ ènìyàn Júdà pẹ̀lú àwọn àlùfaà àti àwọn ọmọ Léfì, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó ti inú Ísírẹ́lì jáde wá, àti àwọn àlejò tí ó ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì jáde wá, àti àwọn tí ń gbé Júdà yọ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ńlá sì wà ní Jérúsálẹ́mù nítorí láti ọjọ́ Sólómónì, ọmọ Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì, irú èyí kò sí ní Jérúsálẹ́mù Nígbà náà ni àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì dìde, wọ́n sì súre fún àwọn ènìyàn náà a sì gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì gòkè lọ si ibùgbé mímọ́ rẹ̀, àni sí ọ̀run Ìdáwó Fún Ìjọ́sìn Nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ti dé òpin, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà níbẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú Júdà, wọ́n fọ́ àwọn òkúta ìyàsọ́tọ̀ sí wẹ́wẹ́, wọ́n gé àwọn òpó Áṣérà lulẹ̀ Wọ́n ba àwọn ibi gíga jẹ́ àti àwọn pẹpẹ Jákè jádò Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti ní Éfíráimù àti Mánásè Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti pa gbogbo wọn run, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà sí ìlú wọn àti sí nǹkan ìní wọn Heṣekíà fi lé àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì lọ́wọ́ sí àwọn ìpín olúkúlùkù wọn gẹ́gẹ́ bí isẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí ará Léfì láti tẹ́ ọrẹ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ láti fi ọpẹ́ fún àti láti kọ àwọn orin ìyìn ní ẹnu ọ̀nà ibùgbé Olúwa Ọba dá láti ara ohun ìni rẹ̀ fun ọrẹ sísun àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti fún ọrẹ sísun ní ọjọ́ ìsinmi, òṣùpá tuntun àti àsè yíyàn gẹ́gẹ́ bi a ti se kọ ọ́ nínú òfin Olúwa Ó pàsẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Léfì, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jìn fún òfin Olúwa Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkóso ti ọkà wọn, ọtí titun òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀ Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti Júdà ti gbe inú àwọn ìlú Júdà pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun Ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkítì Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣiṣe èyí ní oṣù kẹ́ta, wọ́n sì parí ní oṣù kéje Nígbà tí Heṣekáyà àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkítì náà, wọ́n yin Olúwa , pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì Heṣekáyà bèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì nípa òkìtì Sádókù sì dáhùn pé Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì sẹ́kù lọ́pọ̀lọpọ̀ Heṣekáyà pàsẹ láti tọ́jú àwọn yàrá ìpamọ́ nínú ilé Olúwa , wọ́n sì ṣe èyí Nígbà náà wọ́n fi tọkàntọkàn mú ìdáwó wọn wá ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn yíyà sọ́tọ̀ Kónánáyà ará Léfì wà ní ìdí nǹkan wọ̀nyí àti arákùnrin rẹ̀ Ṣíméhì jẹ́ àtẹ̀lé e rẹ̀ lóyè Jéhíélì, Áṣáṣíà, Náhátì, Ásáhélì, Jérímótì, Joábádì, Élíélì, Ísímákíà, Máhátì àti Bénáyà jẹ́ àwọn alábojútó lábẹ́ Konáníà àti Ṣíméhì arákùnrin rẹ̀ nípa ipá ọba Heṣekáyà àti Áṣáríyà oníṣẹ́ ti ó wà ní ìkáwọ́ ilé Ọlọ́run Kórè ọmọ ímínà ará Léfì Olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn, wà ní ìkáwọ́ àwọn ọrẹ àtinúwá tí a fi fún Ọlọ́run, pí pín ìdáwó tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ Édẹ́nì, Miníámínì, Jéṣúà, Ṣemáyà, Ámáríyà àti Ṣekánáyà ràn án lọ́wọ́ tọkàntọkàn nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà tí ń dáwó fún àwọn àlùfáà ẹlẹ́gbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àgbà àti kékeré Ní àfikún, wọ́n pín sí àwọn ọkùnrin àgbà ọdún mẹ́ta tàbi ọ̀pọ̀ tí orúkọ wọn wà nínu ìtàn ìdíle láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn Gbogbo àwọn ti yóò wọ ilé Olúwa láti ṣe oríṣìí iṣẹ́ ti a gbàwọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn àti ìpín wọn Wọ́n sì pín àwọn àlùfáà, wọn kọ orúkọ àwọn ìdílé wọn sínú ìtàn ìdílé àti sí àwọn ará Léfì ogún ọdún tàbí jùbẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpínnu àti ìpín wọn Wọ́n fi gbogbo àwọn ọmọ kékèké sí i, àwọn ìyàwó, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin gbogbo ará ìlu Tí a kọ lẹ́sẹsẹ sínú ìtàn ìdílé yìí ti baba ńlá wọn fún ìrántí Nítorí tí wọ́n ṣe òtítọ́ ní yíya ara wọn sí ọ̀tọ̀ Ní ti àwọn àlùfáà, àwọn ìran ọmọ Árónì, tí ń gbé ni àwọn ilẹ̀ oko lẹ́bàá àwọn ìlú wọn tàbí ní àwọn ìlú mìíràn A yan àwọn ọkùnrin pẹ̀lú orúkọ láti pín ìlú fún gbogbo ọkùnrin láàárin wọn àti sí gbogbo àwọn tí a kọ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá àwọn ará Léfì Èyí ni Heṣekáyà ṣe jákèjadò Júdà, ó sì ṣe ohun tí ó dára àti tí ó tọ́ àti ohun òtítọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, Nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé níti iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Ọlọ́run àti ní ìgbọ́ràn sí òfin àti àwọn àṣẹ Ó wá Ọlọ́run rẹ̀, ó sì ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn Ó sì ṣe rere Senakéríbù Dẹ́rùba Jérúsálẹ́mù Lẹ́yìn gbogbo èyí ti Heṣekíà ti fi otítọ́ se, Senakéríbù ọba Ásíríà wá ó sì gbógun ti Júdà Ó gbógun ti àwọn ìlú ààbò, ó ń ronú láti ṣẹ́gun wọn fún ararẹ̀ Nígbà tí Heṣekáyà rí i pé Senakérébù ti wá, àti pé ó fẹ́ láti dá ogun sílẹ̀ lóri Jérúsálẹ́mù, Ó gbèrò pẹ̀lu àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ tí wọ́n fẹ́rẹ̀ ẹ́ di orísun omi ní ìta ìlú ńlá, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ Ọ̀pọ̀ ogun ọkùnrin péjọ, wọ́n sì dí gbogbo àwọn orísun àti àwọn omi tó ń ṣàn tí ó ń sàn gba ti ilẹ̀ naà Kí ni ó dé tí àwọn ọba Ásíríà fi wá tí wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ omi Wọ́n wí Nígbà náà ó ṣiṣẹ́ gidigidi ní títún gbogbo ìtorí ara ògiri tí ó ti bàjẹ́ ṣe, ó sì ń kọ́ àwọn ilé iṣẹ́ gíga sókè rẹ̀ Ó kọ́ ògiri mìíràn sí ìta ìyẹn Ó sì rán ibi ìfẹ̀yìntì lọ́wọ́ pẹ̀lú ibi ìtẹ́jú ilé níti ìlú ńlá Dáfídì Ó ṣe ọ̀pọ̀ iye ohun ìjà àti àwọn àpáta Ó yan àwọn ìjòyè ológun sórí àwọn ènìyàn, ó sì pèwọ́n jọ, níwájú rẹ̀ ní ìbámu ní ìlú ńlá ti Dáfídì Ó sì ki wọ́n láyà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí Ẹ jẹ́ alágbára, àti kí ẹ sì ní ìgboyà Ẹ má se bẹ̀rù tàbí ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nítorí tí ọba Ásíríà àti ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí agbára ńlá wà pẹ̀lú wa ju òun lọ Agbára ẹran ara nìkan ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣùgbọ́n, pẹ̀lú wa ni Ọlọ́run láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja ìjà wa Àwọn ènìyàn sì ní ìgboyà láti ara ohun tí Hesekía ọba Júdà wí Lẹ́yìn ìgbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ ń gbógun sí Lákíṣì Ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú iṣẹ́ yí fún Heṣekáyà ọba Júdà àti fún gbogbo àwọn ènìyàn Júdà tí ó wà níbẹ̀ Èyí ni ohun tí Senakéríbù ọba Ásíríà wí Lórí kí ni ẹ̀yin gbé ìgbẹ́kẹ̀lé yín lé, tí ẹ̀yin fi dúró sí Jérúsálẹ́mù lábẹ́ ìgbógun sí Nígbà tí Heṣekáyà wí pé Olúwa Ọlọ́run wa yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà, ó ń sì yín tọ́ sọ́nà, kí ẹ bá lè kú fún ebi àti òǹgbẹ Ṣé Heṣekáyà fún ra rẹ̀ kò mú àwọn ọlọ́run ibi gíga àti àwọn pẹpẹ kúrò, tí ó ń wí fún Júdà àti Jérúsálẹ́mù pé Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ kan àti láti sun àwọn ẹbọ lóri rẹ̀ Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ ohun tí èmi àti àwọn bàbá mi ti ṣe sí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn Ǹjẹ́ àwọn Ọlọ́run tí àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ní agbára láti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀ èdè wọ̀nyí tí àwọn baba mi ti parun, tí ó le gbà ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ mi, tí Ọlọ́run yín yóò fi le gbà yín lọ́wọ́ mi Nísinsinyìí, ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà ó tàn yín àti sì yín tọ́ sọ́nà báyìí Ẹ má se gbàá gbọ́, nítorí tí kò sí Ọlọ́run orílẹ̀-èdè mìíràn tàbí ìjọba tí ó ní agbára láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi tàbí lọ́wọ́ àwọn bàbá mi, mélòómélòó wa ni Ọlọ́run yín tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi! Àwọn ìjòyè Senakéríbù sọ̀rọ̀ ṣíwájú síi ní ìlòdì sí Olúwa Ọlọ́run àti sí ìránṣẹ́ rẹ̀ Heṣekáyà Ọba pẹ̀lú sì kọ àwọn ìwé ní bíbú Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti ní sísọ èyí ní ìlòdì sí Ní gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn kò ṣe gba àwọn ènìyàn wọn kúrò lọ́wọ́ mi, Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run Heṣekáyà kì yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi Lẹ́yìn náà wọ́n pè jáde ní èdè Hébérù sí àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì tí ó wà lára ògiri, láti dá ọjọ́ si wọn, ki wọn kí ó lè fi agbára mú ìlú náà Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run Jérúsálẹ́mù bí wọ́n ti ṣe nípa àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn mìíràn ti àgbáyé, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn Ọba Heṣekáyà àti wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì sunkún jáde nínú àdúrà sí ọ̀run nípa èyí Olúwa sì ran ańgẹ́lì tí ó pa gbogbo àwọn oko oníjà àti àwọn adarí àti àwọn ìjòyè tí ó wà nínú àgọ́ ọba Ásíríà run Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí ilẹ̀ rẹ̀ ní ìtìjú Nígbà tí ó sì lọ sínú ilé ọlọ́run rẹ̀, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yọ Heṣekáyà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ Senákéríbù ọba Ásíríà àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn mìíràn Ó tọ́jú wọn ní gbogbo ọ̀nà Ọ̀pọ̀ mú ọrẹ wá sí Jérúsálẹ́mù fún Olúwa àti àwọn ẹ̀bùn iyebíye fún Heṣekáyà ọba Júdà Láti ìgbà náà lọ gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè ni ó kàá sí Ní ọjọ́ wọ̀n nì Heṣekáyà ṣe àárẹ̀, ó sì dójú ikú Ó gbàdúrà sí Olúwa , Tí ó dá a lóhùn, tí ó sì fún un ní àmì àgbàyanu Ṣùgbọ́n ọkàn Heṣekáyà ṣe ìgbéraga, kò sì kọbi ara síi inú rere tí a fi hàn án Nítorí náà, ìbínú Olúwa wà lórí rẹ̀ àti lóri Júdà àti Jérúsálẹ́mù Nígbà náà Heṣekáyà ronú pìwàdà ní ti ìgbéraga ọkàn rẹ̀, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù sì ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ìbínú Olúwa kò wá sí orí wọn ní ìgbà àwọn ọjọ́ Heṣekáyà Heṣekáyà ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá àti ọlá, Ó sì ṣe àwọn ilé ìṣúra fún fàdákà àti wúrà rẹ̀ àti fún àwọn òkúta iyebíye rẹ̀, àwọn tùràrí olóòórùn dídùn àwọn àpáta àti gbogbo oríṣìí nǹkan iyebíye Ó kọ́ àwọn ilé pẹ̀lú láti tọ́jú àwọn ọkà àwọn tí wọ́n ka, ọtí titun àti òróró ó sì ṣe àwọn àtíbàbà fún oríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn àti àwọn àsémọ́ fun àwọn ọ̀wọ̀ ẹran Ó kọ́ àwọn ìletò, ó sì gba ọ̀pọ̀ iye àwọn ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, nítorí tí Olúwa ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá Heṣekíà ni ó dí ojú ìṣúra apá òkè ti orísun Gíhónì Ó sì gbe gba ìsàlẹ̀ sí ìhà ìwọ oòrùn ìlú ńlá ti Dáfídì Ó ṣe àṣeyọrí sí rere nínu gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé Ṣùgbọ́n nígbà tí ara àwọn oníṣẹ́ ọba wá láti Bábílónì láti bi í lérè nípa àmìn ìyanu tí ó sẹlẹ̀ nì, Ọlọ́run fi sílẹ̀ láti dán an wò àti láti mọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ Gbogbo iṣẹ́ yòókù ti ìjọba Heṣekíà àti àwọn ìṣe rẹ̀, ìfarajì rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé ìran wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì nínú ìwé àwọn ọba Júdà àti Ìsírẹ́lì Heṣekáyà sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ A sì sin-ín sórí òkè níbi tí àwọn ibojì àwọn àtẹ̀lé Dáfídì wà Gbogbo Júdà àti àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ni ó bu ọlá fún un nígbà tí ó kú Mánásè ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Mánásè Ọba Júdà Mánásè jẹ́ ọmọ ọdún Méjìlá nígbà tí ó di ọba Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Nípa títẹ̀lé ọ̀nà iṣẹ́ ìríra ti àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn Ó tún kọ́ àwọn ibi gíga tí baba rẹ̀ Heṣekáyà ti fọ́ túútúú Ó sì gbé àwọn pẹpẹ dìde fún àwọn Báálì ó sì ṣe àwọn òpó Áṣérà Ó foríbalẹ̀ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run ó sì sìn wọ́n Ó kọ́ àwọn pẹpẹ sínú ilé Olúwa ní èyí tí Olúwa ti wí pé Orúkọ mi yóò wà ní Jérúsálẹ́mù títí láé Nínú ààfin méjèèje ti ilé Olúwa , ó kọ́ àwọn pẹpẹ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rúbọ nínú iná ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Bẹni-Hínómù, ó ń ṣe oṣó, àfọ̀ṣẹ, ìsàjẹ́ pẹ̀lú bíbéèrè lọ́dọ̀ àwọn abókúsọ̀rọ̀, àti ẹlẹ́mìí O se ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú Ó mú ère gbígbẹ́ tí ó ti gbẹ́ ó sì gbé e sínú ilé Olúwa , ní èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún Dáfídì àti sí ọmọ rẹ̀ Solómónì, Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jérúsálẹ́mù, tí mo ti yàn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, èmi yóò fi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé Èmi kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ilẹ̀ tí a yàn fún àwọn baba ńlá yín tí wọ́n bá ṣe pẹ̀lẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí mo palásẹ fún wọn Nípa gbogbo àwọn òfin, àsẹ àti àwọn ìlànà tí a fún yín ní pasẹ̀ Mósè Ṣùgbọn Mánásè mú kí Júdà àti àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn tí Olúwa ti parun níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ọlọ́run bá Mánásè sọ̀rọ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò kọbi ara sí i Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa mú àwọn alákòóso ọmọ ogun ọba Ásíríà láti dojúkọ wọ́n, tí ó mú Mánásè lẹ́lẹ́wọ̀n, ó fi ìkọ́ mú-un ní imú rẹ̀, ó dè é pẹ̀lú Ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ ó sì mú-un lọ sí Bábílónì Nínú ìpọ́njú rẹ̀, ó wá ojú rere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ Ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ Nígbà tí ó sì gbàdúrà síi, inú Olúwa dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jérúsálẹ́mù àti sí ìjọba rẹ̀ Nígbà náà Mánásè mọ̀ wí pé Olúwa ni Ọlọ́run Lẹ́yìn èyí, ó tún ìta ògiri ìlú ńlá Dáfídì kọ́ Ìhà ìwọ̀ oòrùn orísun Gíhónì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní jìnnà réré bí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ẹja àti yíyí orí òkè Ófélì ó se é ní gíga díẹ̀ Ó mú àwọn alákòóso ológun wà ní ìdúró nínú gbogbo àwọn ìlú ńlá olódi ní Júdà Ó pa gbogbo àwọn Ọlọ́run àjòjì run Ó sì hú gbogbo àwọn ère kúrò nínú ilé Olúwa , pẹ̀lú gbogbo àwọn pẹpẹ tí ó ti kọ́ ní òkè ilé Olúwa àti ní Jérúsálẹ́mù ó sì kó wọn jáde kúrò nínú ìlú Nígbà náà ó mú àwọn pẹpẹ padà bọ̀ sípò Ó sì rú ọrẹ ìdàpọ̀ àti ọrẹ ọpẹ́ lórí rẹ̀ Ó sì sọ fún Júdà láti sin Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì Àwọn ènìyàn, bí ó ti wù kí ó rí, tẹ̀ṣíwájú láti máa rú ẹbọ ní àwọn ibi gíga Ṣùgbọ́n sí Olúwa Ọlọ́run wọn nìkan Àwọn isẹ́ yòókù ti ìjọba Mánásè pẹ̀lú àdúrà rẹ̀ sí Ọlọ́run rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn aríran sọ sí i wà nínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì Àdúrà rẹ̀ àti bí inú Ọlọ́run ṣe dùn sí àdúrà rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti àìsòótọ́ àti àwọn ipò níbi tí ó kọ́ àwọn ibi gíga sí, ó sì gbé àwọn òpó Áṣérà àti àwọn òrìṣà kí ó tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sínu ìwé ìrántí àwọn aríran Mánásè sinmi pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín sínú ààfin rẹ̀ Ámónì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ámónì jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjì Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa , gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ Mánásè ti ṣe Ámónì sìn ó sì rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà tí Mánásè ti ṣe Ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i baba a rẹ̀ Mánásè Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Olúwa Ẹ̀bi Ámónì ń ga sí i Àwọn onísẹ́ Ámónì dìtẹ̀ síi Wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀ Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Ámónì, wọ́n sì mú Jósíà ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀ A rí Ìwé òfin Jósíà sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì dí ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n Ó sì ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa , ó sì rìn ọ̀nà baba rẹ̀ Dáfídì, kò sì yà sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí òsì Ní ọdún kẹ́jọ ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó sì wà ní ọ̀dọ́mọdé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí íwá ojú Ọlọ́run Baba Dáfídì Ní ọdún kéjìlá Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wẹ Júdà àti Jérúsálẹ́mù mọ́ kúrò ní ibi gíga rẹ̀, ère òrìṣà, àti ère yíyá àti ère dídà Lábẹ́ àpẹẹrẹ àwọn pẹpẹ Bálímù ni a yí lulẹ̀, ó sì fọ́ àwọn ère sí wẹ́wẹ́, ó run àwọn pẹpẹ tí ó wà lórí rẹ̀, wọ́n sì fọ́ túútúú àti àwọn ère dídá, àwọn òrìṣà àti ère dídá Èyí tí ó fọ́ wọn sì lùúlùú, ó sì gbọ̀n wọ́n sí orí ìsà òkú àti àwọn tí ó ń rúbọ sí wọn Ó sì sun àwọn egungun àwọn àlùfáà lórí pẹpẹ wọn, Bẹ́ẹ̀ sì ni ó sì wẹ Júdà àti Jrusálẹ́mù mọ́ Ní ìlú Mánásè, Éfíráímù àti Síméónì, àní títí ó fi dé Náfítalì, àti nínú àwọn, ó tú ilé wọn yíkáyíká Ó sì wó pẹpẹ àti ère òrìṣà lulẹ̀ àti àwọn ère yíyá àti àwọn òrìṣà, ó sì gùn ó sì ti ké gbogbo àwọn ère orí pẹpẹ lulẹ̀ ní gbogbo àyíká Ísírẹ́lì Lẹ́yìn náà ó padà sí Jérúsálẹ́mù Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jósíà ni a ti wẹ ilẹ̀ náà mọ́ àti ilé Olúwa , ó sì rán Ṣáfánì ọmọ Ásálíà àti Màséíà olórí ìlú náà, pẹ̀lú Jóà, ọmọ Jóáhásì, akọ̀wé, láti tún ilé Olúwa Ọlọ́run ṣe Wọ́n sì lọ sí ọ̀dọ̀ Hílíkíyà olórí àlùfáà, ó sì fún-un ní owó náà tí ó mú wá sí ínú ilé Ọlọ́run, ti àwọn ọmọ Léfì ẹni tí ó jẹ́ aṣọ́-ẹnú-ọ̀nà-ìbòdè ti gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Ménásè Éfíráímù àti láti ọ̀dọ̀ Àwọn ìyókù Ísírẹ́lì àti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn Júdà àti Bẹ́ńjámínì wọ́n sì padà sí Jérúsálẹ́mù Nígbà náà wọn si fi le àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ilé lọ́wọ́, àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ ilé Olúwa Àwọn ọkùnrin yìí sì san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ṣe, tí wọ́n sì ń ṣìṣẹ́ ní ilé Olúwa Wọ́n sì tún fi owó fún àwọn ọlọ́nà àti àwọn olùkọ́lé láti ra òkúta gbígbẹ́ àti ìtì igi fún ìsopọ̀ àti igi rírẹ́ fún ìkọ́lé tí ọba Júdà ti gbà láti tẹ́ ilé tí wọ́n ti bàjẹ́ Àwọn ọkùnrin náà ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú òtítọ́ lórí wọn, láti darí wọn ní Jáhátì àti Obadíà, àwọn ọmọ Léfì láti Mérárì, àti Sekaríà àti Mèsúlámù, sọ̀kalẹ̀ láti Kónátì àwọn ọmọ Léfì gbogbo tí ó ní ọgbọ̀n ohun èlò orin Wọ́n sì ní olórí àwọn aláàárù àti àwọn alábojútó gbogbo àwọn òṣìsẹ́ láti ibisẹ́ si ibisẹ́, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Léfì sì ní alákọ̀wé, olùtọ́jú àti olùsọ́nà Nígbà tí wọ́n mú owó náà tí wọ́n mú wá sí ilé Olúwa , Hílkíà àlùfáà sì rí ìwe òfin Olúwa tí a ti fi fún-un láti ọwọ́ Mósè Hílíkíyà sì wí fún Ṣáfánì akọ̀wé pé, Èmi ti rí ìwe òfin nínú ilé Olúwa Ó sì fi fún Ṣáfánì Nígbà náà Ṣáfánì sì mú ìwé náà lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ó sì ròyìn fún-un Àwọn ìjòyè rẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan tí a ti fi lé wọn lọ́wọ́ Wọ́n ti san owó náà tí ó wà nínú ilé Olúwa wọ́n sì ti fi lé àwọn alábojútó lọ́wọ́ àti àwọn òṣìsẹ́ Nígbà náà Ṣáfánì akọ̀wé sì sọ fún ọba, Hílíkíyà àlùfáà ti fún mi ní ìwé Ṣáfánì sì kà níwájú ọba Nígbà tí ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya Ó sì pa àṣẹ yìí fún Hílíkíyà, Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì, Ábídónì ọmọ Míkà, Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáíà ìránṣẹ́ ọ̀nà Ẹ lọ kí ẹ lọ bérè lọ́wọ́ Olúwa fún mi fún àwọn ìyókù Ísírẹ́lì àti Júdà nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́, wọn kò sì tíì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí Híkíánì àti àwọn ènìyàn tí a yàn sì lọ láti sọ̀rọ̀ sí àwọn wòlíì Húlídà aya Ṣálúmù ọmọ Tókátì, ọmọ Hásíràh, olùtọ́jú ibi ìkásọsí, ó sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ní ìhà kejì Ó sì wí fún wọn wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti sọ, sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Júdà Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ wọ́n sì ti sun tùràrí sí ọlọ́run mìíràn wọ́n sì ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn ṣe, ìbínú yóò tú jáde wá sórí ibíyìí, a kì yóò sì paná rẹ̀ Sọ fún ọba Júdà, ẹni tí ó rán yín láti bèèrè lọ́wọ́ Olúwa , Èyí ni ohun tí Olúwa ti sọ, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nípa ọ̀rọ̀ wọ̀n nì tí íwọ gbọ́ Nítorí ọkàn rẹ̀ dúró ìwọ sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa nígbà tí ó gbọ́ ohun tí ó sọ lórí ibíyìí àti ènìyàn rẹ, nítorí ìwọ rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi tí o sì fa aṣọ rẹ ya, tí o sì lọ níwájú mi Èmi ti gbọ́ tìrẹ ni Olúwa wí Nísinsinyìí, Èmi ó kó ọ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ àwọn baba rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà Ojú rẹ kò sì ní rí gbogbo ibi tí èmi ó mú wá sórí ibíyìí àti lórí àwọn tí ń gbé ibẹ̀   Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé ìdáhùn rẹ̀ padà sí ọ̀dọ̀ ọba Nígbà náà ọba sì pe gbogbo àwọn àgbààgbà Júdà jọ àti Jérúsálẹ́mù Wọ́n sì lọ sókè ní ilé Olúwa pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Júdà, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì gbogbo ènìyàn lati ẹní ńlá sí ẹní kékeré, ó sì kà á ní etí wọn gbogbo ọ̀rọ̀ ínú ìwé májẹ̀mú, tí wọ́n ti rí nínú ilé Olúwa Ọba sì dúró ní ipò rẹ̀ ó sì tún májẹ̀mú dá níwájú Olúwa láti tẹ̀lé Olúwa àti láti pa ofin rẹ̀ mọ́, àti ẹ̀rí rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo àyà rẹ̀ àti láti pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sí ínú ìwé yìí Nígbà náà, ó sì mú kí gbogbo ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù àti Bẹ́ńjámínì dúró nínú ẹ̀rí fún ara wọn, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ṣe èyí gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú Ọlọ́run, Ọlọ́run Baba wọn Jósíà sì kó gbogbo ohun ìríra kúrò nínú gbogbo ìlú tí ń ṣe ti àwọn tí ó wà ní Ísírẹ́lì, ó sì mú kí gbogbo àwọn tí ó wà ní Ísírẹ́lì sin Olúwa Ọlọ́run wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà láyè wọn, kò yà kúrò láti máa tọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn lẹ́yìn Jósíà Ṣe Ìrántí Àjọ Ìrékọjá Síwájú síi, Jósíà ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, Àjọ ìrékọjá náà ni wọ́n sì pa ẹran ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ní-ní Ó sì yàn àwọn àlùfáà sí iṣẹ́ wọn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú ní ìsìn ilé Olúwa Ó sì wí fún àwọn ọmọ Léfì, ẹni tí ó sọ fún gbogbo àwọn Ísírẹ́lì ẹni tí a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa pé ẹ gbé àpótí ẹ̀rí ìyàsọ́tọ̀ sí ilé Olúwa tí Sólómónì ọmọ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ti kọ́ Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹrù àgbéká ní èjìká rẹ̀ Nísinsìn yìí ẹ sin Olúwa Ọlọ́run yín àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì Ẹ múra sílẹ̀ nípa ìdílé ní ẹsẹsẹ yín gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ tí a kọ́ láti ọwọ́ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ Sólómónì Dúró ní ibi mímọ́ pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Léfì fún ọ̀kọ̀kan ìpín àwọn ìdílé àwọn ẹgbẹ́ ará ìlú, àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀ Ẹ pa ẹran àjọ ìrékọjá náà, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì pèsè ẹ̀ran fún àwọn ẹgbẹ́ arákùnrin yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa paláṣẹ láti ọwọ́ Mósè Jósíà sì pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀ tí ó wà níbẹ̀ iye rẹ̀ ẹgbàámẹ́ẹ̀dógún ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọmọ ewurẹ́ fún ẹbọ ìrékọjá, àti pẹ̀lú ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n akọ màlúù gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ohun ìní láti ọ̀dọ̀ ọba Àwọn ìjòyè rẹ̀ fi tinútinú ta àwọn ènìyàn náà ní ọrẹ àti àwọn Àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì Hílíkíyà, Sekaríà àti Jéhíélì, àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀tàlá ẹbọ àjọ ìrékọjá àti ọ̀ọ́dúnrún ẹran ọ̀sìn Àti pẹ̀lú Koníà àti pẹ̀lú Ṣémíà àti Nàtaníẹ́lì, àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti Haṣabíà, Jélíélì àti Joábádì olórí àwọn ọmọ Léfì, ó sì pèsè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ẹbọ ìrékọjá àti ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n orí ẹran ọ̀sìn fún àwọn ọmọ Léfì Nítorí náà, a múra ìsìn náà sílẹ̀, àwọn àlùfáà sì dúró ní ipò wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nípa iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á lásẹ Ní ti àjọ ìrékọjá a sì pa ẹran, àwọn àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà tí wọ́n gbé sí ọwọ́ wọn, nígbà tí àwọn ọmọ Léfì sì bo ẹranko Wọ́n sì ya àwọn ẹbọ sísún sí apá kan láti fi wọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ìdílé àwọn ènìyàn láti rúbọ sí Olúwa Gẹ́gẹ́ bí a ti kọọ́ sínú ìwé Mósè Wọ́n sì se bákan náà pẹ̀lú àwọn ẹran ọ̀sìn Wọ́n sì fi sun àjọ ìrékọjá lórí iná Gẹ́gẹ́ bí ìlànà, wọ́n sì bọ ẹbọ mímọ́ nínú ìkòkò, nínú odù àti nínú agbada, wọ́n sì pín wọn kíákía fún gbogbo àwọn ènìyàn Lẹ́yìn èyí, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà nítorí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Árónì, ni wọ́n rú ẹbọ sísun àti ọ̀rá títí di àsálẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ Árónì àlùfáà Àwọn akọrin, àwọn ọmọ Ásáfù, ni wọ́n wà ní ipò wọn tí a sì paláṣẹ fún wọn láti ọwọ́ Dáfídì, Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì àwọn aríran ọba àti àwọn olùsọ́nà ní olúkúlùkù ẹnu ọ̀nà kò gbọdọ̀ fi ojú ọ̀nà wọn sílẹ̀, nítorí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ti múra sílẹ̀ fún wọn Bẹ́ẹ̀ ni àsìkò náà gbogbo àwọn ìsìn Olúwa ni wọ́n gbé jáde fún iṣẹ́ ìrántí àjọ ìrékọjá àti láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Olúwa , gẹ́gẹ́ bí ọba Jósíà ti paá lásẹ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó gbé kalẹ̀ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá ní àkókò náà àti àjọ àkàrà àìwú fún ọjọ́ méje Àjọ ìrékọjá náà kòsì tí ì sí èyí tí ó dàbí i rẹ̀ ní Ísírẹ́lì títí dé ọjọ́ wòlíì Sámúẹ́lì, kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ọba Ísírẹ́lì tí ó pa irú àjọ ìrékọjá bẹ́ẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Jósíà ti se, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo àwọn Júdà àti Ísírẹ́lì tí ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Jérúsálẹ́mù Àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí ní ọdún kejìdínlogún ìjọba Jósíà Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Jósíà ti tún ilẹ̀ náà se tán, Nékò ọba Éjíbítì gòkè lọ láti bá Keríkemísì jà lórí odo Éúfírátè, Jósíà sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà Ṣùgbọ́n Nékò rán ìránṣẹ́ sí i wí pé, Ìjà wo ni ó ń bẹ láàrin èmi àti ìwọ, ọba Júdà Kìí se ìwọ ni èmi tọ̀ wá ní àkókò yìí, ṣùgbọ́n, ilé pẹ̀lú èyí ti mo bá níjà Ọlọ́run ti sọ fún mi láti yára àti láti dúró nípa ṣíṣe ìdènà Ọlọ́run, ẹni tí ó wà pẹ̀lú mi, kí òun má bàá pa ọ́ run Jósíà, bí ó ti wù kí ó rí, ẹni tí kò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ara rẹ̀ dà kí ó le báa jà, kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọ́run ṣùgbọ́n ó lọ láti jà lórí àfonífojì Mégídò Tafàtafà sì ta ọfà sí ọba Jósíà, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè pé, Ẹgbé mi kúrò, èmi sì ti gba ọgbẹ́ gidigidi Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbé e jáde kúrò nínú kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n sì gbé e sínú kẹ̀kẹ́ mìíràn, wọ́n sì gbé e wá sí Jérúsálẹ́mù, níbi tí ó ti kú, wọ́n sì sin ín sínú ọ̀kan nínú àwọn ibojì àwọn baba rẹ̀, gbogbo Júdà àti gbogbo Jérúsálẹ́mù sì sọ̀fọ̀ fún un Jeremáyà sì pohùn réré ẹkún fún Jósíà, gbogbo àwọn akọrin ọkùnrin àti gbogbo àwọn akọrin obìnrin sì ń sọ ti Jósíà nínú orin ẹkún wọn títí di òní Èyí sì di àṣà ní Jérúsálẹ́mù, a sì kọọ́ sínú àwọn orin ẹkún Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Jósíà àti ìwà rere rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a ti kọ sínu ìwé òfin Olúwa Gbogbo iṣẹ́ náà, àti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì àti Júdà Jehóáhásì Ọba Júdà Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehóáhásì ọmọ Jósíà wọn sì fi jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù ni ipọ̀ Baba rẹ̀ Jehóáhásì sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ni Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́ta Ọba Éjíbítì lé e kúrò lórí ìtẹ́ ní Jérúsálẹ́mù ó sì bù fún un lórí Júdà, ọgọ́rún talẹ́ńtì fàdákà àti talẹ́ntì wúrà kan Ọba Éjíbítì sì mú Élíákímù, arákùnrin Jehóáhásì, jẹ ọba lórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù, ó sì yí orúkọ Eliákímù padà sí Jéhóíákíámù, ṣùgbọ́n Nékò mú arákùnrin Eliákímù, Jehóáhásì ó sì gbé e lórí Éjíbítì Jéhóíákímù sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìlá Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ Nebukadínésárì ọba Bábílónì sì mú un, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti mú-un lọ sí Bábílónì Nebukadínésárì pẹ̀lú mú-un lọ sí Bábílónì, ohun èlò láti ilé Olúwa , ó sì mú wọn lọ sí ààfin tirẹ̀ níbẹ̀ Ìyòókù isẹ́ ìjọba Jéhóíákíámù, àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti gbogbo ohun tí a rí nípa rẹ̀, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì àti Júdà Jéhóíákínì ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀ Jehóiakínì sì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ́ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta àti ijọ́ mẹ́wàá ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ní àmọ́dún, ọba Nebukadínsárì ránsẹ́ síi ó sì mú-un wá sí Bábílónì, pẹ̀lú ohun èlò dáradára láti ilé Olúwa , ó sì mú arákùnrin Jehóíákínì, Sedekíà, jọba lórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù Sedekíáyà sì jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlèlógún Nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlá Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ ko si rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jeremíà wòlíì, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ Olúwa Ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Nebukadinésárì pẹ̀lú, ẹni tí ó mú kí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra Ó sì di ẹni tí ọrùn rẹ̀ wàkì, ó sì mú ọkàn rẹ̀ le láti má lè yípadà sí Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì Síwájú síi gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn sì di ẹni tí ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú gbogbo ìríra àwọn orílẹ̀ èdè wọ́n sì sọ ilé Olúwa di èérí, tí ó ti yà sí mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù Olúwa , Ọlọ́run àwọn baba wọn ránsẹ́ sí wọn láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣíwájú àti ṣíwájú síi, nítorí tí ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti sí ibùgbé rẹ̀ Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùn sí àwọn ìransẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n fi àwọn wòlíì rẹ̀ sẹ̀sín títí tí ìbínú Ọlọ́run ṣe ru sórí wọn, sí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì sí àtúnṣe Ó sì mú wá sórí wọn ọba àwọn ará Bábílónì tí wọ́n bá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn jà pẹ̀lú idà ní ilẹ̀ ibi mímọ́, kò sì ní ìyọ́nú sí àgbà ọkùnrin tàbí ọ̀dọ́mọdé bìnrin, wúndíá, tàbí arúgbó Ọlọ́run sì fi gbogbo wọn lé Nebukadinésárì lọ́wọ́ Ó sì mú gbogbo ohun èlò láti ilé Ọlọ́run lọ sí Bábílónì, níńlá àti kékeré àti ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ọba àti ìjòyè rẹ̀ Wọ́n sì fi iná sí ilé Ọlọ́run, wọ́n sì wó gbogbo ògiri ilé Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì jó gbogbo ààfin wọn, wọ́n sì ba gbogbo ohun-èlò ibẹ̀ jẹ́ Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Bábílónì àwọn tí ó rí ibi sá láti ẹnu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Pásíà fi gba agbára Ìlẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí ó fi di àádọ́rin ọdún fi pé ní ìmúsẹ ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ láti ẹnu Jeremíà Ní ọdún kín-ín-ní Kírúsì ọba Pásíà, kí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a tẹnu Jeremáyà sọ báà le ṣẹ pé, Olúwa run ẹ̀mí Kírúsì ọba Pásíà láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọọ́ sínú ìwé pẹ̀lú Èyí ni ohun tí Kérúsì ọba Pásíà sọ wí pé   Olúwa , Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mí ní gbogbo ìjọba ayé yìí, ó sì ti yàn mí láti kọ́ ilé Olúwa fún òun ní Jérúsálẹ́mù ti Júdà Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàárin yín le gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀ kí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀   Àwọn Ìpèsè Fún Ilé Ó se pẹpẹ idẹ, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá fún gíga Ó ṣe agbada dídà ńlá tí ó rí róbótó ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé etí èkejì ìgbọ̀nwọ́ márùn ún sì ni gíga rẹ̀ Lábẹ́ etí, àwòrán àwọn akọ màlúù yíká mẹ́wàá sí ìgbọ̀nwọ́ kan Àwọn akọ màlúù náà ni á dá ní ọ̀nà méjì ní àwòrán kan pẹ̀lú okùn Okùn náà dúró lóri akọ màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúsù mẹ́ta kọjú sí ìlà oòrùn Òkun náà sì sinmi lórí wọn àti gbogbo ìhà ẹ̀yìn wọn sì wà ní apá àárin Ó nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dà bí etí ife ìmumi, bí i ìtànná lílì ó sì dá ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dógun ìwẹ̀ dúró Ó ṣe pọnunpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúṣù àti márùn ún ní àríwá Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ọrẹ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo òkun fún fífọ nǹkan Ó ṣe ìgbe fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé Olúwa márùn un ní ìhà gúsù àti márùn ún ní ìhà àríwá Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé Olúwa , márùn un ní gúṣù àti márùn ún ní ìhà àríwá Ó ṣé ọgọ́rún ọpọ́n ìbùwọ̀n wúrà Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ Ó gbé òkun náà ka orí ìhà gúsù ní ẹ̀bá Igun gúsù àríwá Ó ṣe àwọn kòkò pẹ̀lu, àti ọkọ́ àti àwọn ọpọ́n ìbùwọ́n Bẹ́ẹ̀ ni Húrámì parí iṣẹ́ tí ó ti dáwọ́lé fún ọba Sólómónì ní ilé Ọlọ́run Àwọn òpó méje àwọn ọpọ́n méjì rìbìtì tí ó wà lóri òpó méjèèje náà àti ìṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì láti bo ọpọ́n rìbìtì náà tí ó wà lórí àwọn òpó naà Ọgọ́rùn ún mẹ́rin Pomígíránátì fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì naà, ẹṣẹ̀ méjì Pomigiranati ni fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n kan, láti bo ọpọ́n rìbìtì méjì náà tí ó wà lóri àwọn òpó náà Ó sì ṣe àgbéró ó sì ṣe agbada sí orí wọn Agbada ńlá kan àti màlúù méjìlá lábẹ́ rẹ̀ Àwọn ìkòkò àti ọ̀kọ̀ àti àmúga ẹran àti gbogbo ohun èlò tí ó fara pẹ́ẹ Gbogbo ohun èlò ti Húrámí-bì fi idẹ dídán ṣe fún Sólómónì ọba, fún ilé Olúwa jẹ́ idẹ dídán Ọba dà wọ́n ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì ní àárin méjì Súkótì àti Ṣárétánì Gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí Sólómónì ṣe ní iye lórí púpọ̀ tí a kò le mọ ìwọ̀n iye idẹ tí ó wọ̀n Sólómónì pẹ̀lú ṣe gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Ọlọ́run pẹpẹ wúrà tábìlì èyí tí àkàrà ìfihàn wà lórí rẹ̀ Àwọn ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe pẹ̀lú fìtílà wọn kí wọn lè máa jó gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ní iwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi lélẹ̀ Pẹ̀lú ìtànná wúrà àti fìtílà àti ẹ̀mú Pẹ̀lú àlùmágàjí fìtílà, àti àwo-kòtò àti ṣíbí àti àwo-kòtò tùràrí àti àwọn ìlẹ̀kùn wúrà ti inú tẹ́ḿpìlì àwọn ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ sí ibi mímọ́ jùlọ àti àwọn ìlẹ̀kùn àbáwọ inú gbọ̀ngàn ńlá A gbé Àpótí Ẹ̀rí Wọ Inú Tẹ́ḿpìlì Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Sólómónì ti ṣe fún tẹ́ḿpìlì ti parí, ó kó gbogbo àwọn nǹkan tí Dáfìdì baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò ọ̀sọ́, ó sì fi wọ́n sínú ìsúra ilé Ọlọ́run Nígbà náà ni Sólómónì pe àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ sí Jérúsálẹ́mù, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan àti àwọn olóyè àwọn ìdílé Ísírẹ́lì, kí wọn kí ó gbé àpótí ẹ̀rí Májẹ̀mu Olúwa gòkè wá láti síónì ìlú Dáfídì Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì péjọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní àkókò àjọ àgọ́ Gbogbo àwọn àgbààgbà Isirẹ́lì sì wá, àwọn ọmọ Léfì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí náà gòkè àti àgọ́ ìpàdé àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́ Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì ni ó mú wọn gòkè wá Nígbà náà ni ọba Sólómónì àti gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì tí ó pé jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wà níwájú àpótí ẹ̀rí náà wọ́n sì fi àgùntàn àti màlúù tí a kò leè kà tán rúbọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò leè mọ iye wọn tán nítorí bí wọ́n ti pọ̀ tó Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀ri ti májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa , ibi mímọ́ jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù Àwọn Kérúbù na ìyẹ́ wọn bo ibi àpótí ẹ̀rí náà àti àwọn ọ̀pá tí ó gbé e ró Àwọn ọ̀pá rẹ̀ náà gùn tó bẹ́ẹ̀ tí a fi rí ori àwọn ọ̀pá náà láti ibi àpótí ẹ̀rí náà níwájú ibi mímọ́ náà, ṣùgbọ́n a kò rí wọn lóde Níbẹ̀ ni ó sì wà títí di òní yìí Kò sí ohun kan nínú àpótí ẹ̀rí náà bí kò ṣe síléètì méjì tí Mósè fi sínú rẹ̀ ní Hórébù, ní ìgbà tí Olúwa fi bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì Lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà jáde wá láti ibi mímọ́ Gbogbo àwọn àlùfáà tí ó wà níbẹ̀ ni ó ya ara wọn sí mímọ́ láìbìkítà fún ìpín wọn Gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọ̀kọrin Ásáfù, Hémánì, Jédútúnì àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ẹbí wọn, wọ́n dúró ní igun ìlà oòrùn pẹpẹ náà wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ túntún wọ́n ń lo ohun èlò orin kínnbálì, hápù àti líà Ìwọ̀n ọgọ́fà àwọn àlùfaà tí wọ́n ń fun ìpè ni wọ́n tẹ̀lé wọn Àwọn afọ̀npè àti àwọn ọ̀kọrin pa ohùn wọn pọ̀ sí ọ̀kan soso, láti fi ìyìn àti ọpẹ́ fun Olúwa Wọ́n fi ìpè, kíḿbálì àti àwọn ohun èlò orin mìíràn mọ́ ọn, wọ́n gbé ohùn wọn sokè láti fi yin Olúwa , wọ́n ń kọrin pé Ó dára ìfẹ́ rẹ̀ wà títí láéláé Nígbà náà ni ìkùku ojú ọ̀run kún inú tẹ́ḿpìlì Olúwa , Tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn àlùfáà kò leè ṣiṣẹ́ ìsìn wọn nítorí ìkùku náà, nítorí ògo Olúwa kún inú tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run Sólómónì Gba Àdúrà Ìyà-Sí-Mímọ́ Nígbà náà ni Sólómonì wí pé, Olúwa ti sọ wí pé òun yóò máa gbé nínú ìkùku tí ó ṣú biribiri ṣùgbọ́n èmi ti kọ́ tẹ́ḿpìlì dáradára fún ọ ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láé Ní ìgbà tí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì dúró níbẹ̀, ọba yíjú padà ó sì fi ìbùkún fún gbogbo wọn Nígbà náà ni ó sì wí pé Ògo ni fún Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ mú ohun tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dáfídì baba mi ṣẹ Nitorí tí ó wí pé, Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, èmi kò yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, láti kọ́ ilé, kí orúkọ mi kí ó lè wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yan ẹnikẹ́ni láti jẹ́ olórí lórí Ísirẹ́lì ènìyàn mi Ṣùgbọ́n nísinyìí èmi ti yan Jérúsálẹ́mù, kí orukọ mi leè wà níbẹ̀, èmi sì ti yan Dáfídì láti jọba lórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi Baba mi Dáfídì ti ní-in lọ́kàn láti kọ́ tẹ́ḿpìlì fún orúkọ Olúwa , àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Dáfídì baba mi pé, Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ tẹ́ḿpìlì yìí fún orúkọ mi, ìwọ ṣe ohun dáradára láti ní èyí ní ọkàn rẹ̀ Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ tẹ́ḿpìlì náà, bí kò ṣe ọmọ rẹ, ẹni tí o jẹ́ ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ òun ni yóò kọ́ tẹ́ḿpìlì fún orúkọ mi Olúwa sì ti mú ìléri rẹ̀ ṣẹ Èmi ti dìde ní ipò Dáfídì baba mi, a sì gbé mi ka ìtẹ́ Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣe ìlérí, èmi sì ti kọ́ tẹ́ḿpìlì fún orúkọ Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì Níbẹ̀ ni èmi sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí, nínú èyí ti májẹ̀mú ti Olúwa bá àwọn Ísirẹ́lì ènìyàn mi dá wà Nígbà naà ni Sólómónì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa , ní iwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Isírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ọ rẹ̀ méjèèjì Sólómónì ṣe àga idẹ kan tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ márùn ún fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga, a gbé e sí àárin àgbàlá ti òde Ó sì dúró ní orí rẹ̀, àti pé ó kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Isírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ọ rẹ̀ méjèèjì sí òkè ọ̀run Ó wí pé Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tí ó dà bí rẹ ní ọ̀run àti ní ayé ìwọ tí o pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi tọkàntọkàn wọn rìn ní ọ̀nà rẹ Ìwọ tí o pa ìlérí tí o ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì baba mi mọ́ nítorí ìwọ ti fi ẹnu rẹ ṣe ìlérí àti pé ìwọ ti fi ọwọ́ rẹ mú un ṣẹ bí ó ti rí lónìí yìí Nísinsinyìí Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, pa ìlérí tí ó ti ṣe mọ́ fún ìransẹ́ rẹ Dáfídì baba mi nígbà tí o wí pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ kù láti ní ọkùnrin láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Isírẹ́lì, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n bá kíyèsíara nínú gbogbo ohun tí wọ́n ṣe láti rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí òfin mi gẹ́gẹ́ bí o sì ti ṣe Nísinsìnyí, Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti sèlérí fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì kí ó wá sí ìmúṣẹ Ṣùgbọ́n ṣé Ọlọ́run nítòótọ́ yóò máa bá àwọn ènìyàn gbé lórí ilẹ̀ ayé bí Ọ̀run, àti ọ̀run gíga kò le gbà ọ́ Báwo ni ó ṣe kéré tó, ilé Olúwa tí mo ti kọ́!, Síbẹ̀ ṣe àfiyèsí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún àánú, Olúwa Ọlọ́run mi, gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ Kí ojú rẹ kí ó lè sí sí ilé Olúwa ní ọ̀sán àti lóru, ní ibí yìí tí ìwọ ti wí pé ìwọ yóò fi orúkọ rẹ síbẹ̀ Kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà lórí ibí yìí Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà lórí ibí yìí Gbọ́ láti ọ̀run, ibùgbé rẹ, nígbà tí ìwọ bá sì gbọ́, dáríjìn Nígbà tí ọkùnrin kan bá sì ṣe aburú sí aládùúgbò rẹ̀ tí ó sì gbà kí ó ṣe ìbúra tí ó sì wá tí o sì búra níwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé Olúwa yìí, Nígbà naà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dáhùn Ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ, san padà fún ẹni tí ó jẹ̀bi nípa mímú padà wá sí orí òun tìkárarẹ̀ ohun tí ó ti ṣe Ṣe ìdáláre fún olódodo, bẹ́ẹ̀ sì ni, fi fún-un gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀ Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì bá ní ìjákulẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá nítorí wọ́n ti dẹ́sẹ̀ sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá sì yípadà, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ nínú ilé Olúwa yìí, Nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jìn wọ́n kí o sì mú wọn padà wá sílé tí o ti fi fún wọn àti àwọn bàbá wọn Nígbà tí a bá ti ọ̀run tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́sẹ̀ sí ọ, Nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú, Nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nínú èyí tí wọn ó má a rìn, kí o sì rán òjò lórí ilẹ̀ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ fún ìní Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-àrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, irúgbà tàbí ẹlẹ́ǹgà, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá yọ wọ́n lẹ́nu nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú wọn, ohunkóhun, ìpọnjú tàbí àrùn lè wá, Nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì olúkúlùkù mọ̀ nípa ìpọ́njú rẹ̀ àti ìbànújẹ́, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé Olúwa yìí Nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run ibùgbé rẹ dáríjì, kí o sì pín fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí i gbogbo ohun tí ó ṣe, nígbà tí ìwọ ti mọ ọkàn rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni kí wọn kí ó lè bẹ̀rù rẹ kí wọn kí ó sì rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń gbé nínú ilé tí o ti fi fún àwọn baba wa Ní ti àwọn àlejò tí wọn kò sí lára àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì ṣùgbọ́n tí wọ́n wá láti ọ̀nà jínjìn nítorí orúkọ ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá wá tí ó sì gbàdúrà lórí ilé Olúwa yìí Nigbà náà, gbọ́ láti ọ̀run àni láti ibi ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe ohun tí àwọn àlejò béèrè lọ́wọ́ rẹ Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ènìyàn ayé kí wọn lè mọ orúkọ rẹ kí wọn sì bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ ti se, kí wọn kí ó sì lè mọ̀ wí pé ilé yìí tí èmi ti kọ, orúkọ rẹ ni ó ń jẹ́ Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá lọ sójú ogun lórí àwọn ọ̀ta wọn, nígbàkígbà tí o bá rán wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ lórí ìlú yìí tí ìwọ ti yàn àti ilé Olúwa tí èmi ti kọ́ fún orúkọ rẹ Nígbà náà gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró Nígbà tí wọ́n bá sì dẹ́sẹ̀ sí ọ-nítorí kò sí ènìyàn kan tí kò dẹ́sẹ̀-bí o bá sì bínú sí wọn tí o bá sì fi wọ́n fún àwọn ọ̀tá, tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré tàbí nítòsí, Ṣùgbọ́n, nígbà tí, wọ́n bá sì yí ọkàn wọn padà ní ilẹ̀ tí wọ́n ti mú wọn ní ìgbèkùn, tí wọ́n sì ronú pìwàdà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọn ó sì wí pé, Àwa ti dẹ́sẹ̀, àwa sì ti ṣe ohun tí kò dára, a sì ti ṣe búburú Tí wọn bá sì yípadà sí ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti ẹ̀mí ní ilẹ̀ ìgbèkùn wọn níbi tí wọ́n ti mú wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà wọn, lórí ìlú tí ìwọ ti yàn àti lórí ilé Olúwa tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ Nígbà náà, láti ọ̀run, ibi ibùgbé rẹ, gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jìn wọn, tí ó ti dẹ́sẹ̀ sí ọ Nísinsinyìí, Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ojú rẹ kí ó sí kí o sì tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ fún àdúrà sí ibíyí Ǹjẹ́ nísinsin yìí dìdé, Olúwa Ọlọ́run mi, sí ibi ìsinmi rẹ, ìwọ àti àpótí ẹ̀rí agbára rẹ Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, Olúwa Ọlọ́run mi, kí o wọ̀ wọ́n lásọ pẹ̀lú ìgbàlà, jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ kí inú wọn kí ó dùn nínú ilé rẹ Olúwa Ọlọ́run mi, má ṣe kọ̀ ẹni àmìn òróró rẹ Rántí ìfẹ́ ńlá tí ó ṣe ìlérí fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ Ìyà Símímọ́ Ilé Nígbà tí Sólómónì sì ti parí àdúrà, iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó ọrẹ sísun àti ẹbọ, ògo Ọlọ́run sì kún ilé Olúwa Àwọn àlùfáà wọn kò sì le wo ilé Olúwa náà nítorí pé ògo Olúwa kún un Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí iná tí ó ń sọ̀kalẹ̀ àti ògo Olúwa lórí ilé Olúwa náà, wọ́n sì kúnlẹ̀ lórí eékún wọn pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀, wọ́n sì sin Olúwa , wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa wí pé, Nítorí tí ó dára àánú rẹ̀ sì dúró títí láéláé Nígbà náà ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn sì rú ẹbọ níwájú Olúwa Ọba Sólómónì sì rúbọ ọrẹ ti ẹgbà á mọ́kànlá , orí màlúù àti àgùntàn àti ọkẹ́ mẹ́fà àgùntàn àti ẹranko Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn ya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ Àwọn àlùfáà dúró ní àyè wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Léfì ti ṣe pẹ̀lú ohun èlò orin Olúwa , tí ọba Dáfídì ti ṣe fún ìyìn Olúwa àti tí á lò nígbà tí ó dúpẹ́, wí pé, àànú rẹ̀ sì dúró láéláé, níwájú àwọn ọmọ Léfì, àwọn àlùfáà sì fọn ipè, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dúró Sólómónì sì yà sọ́tọ̀ láàrin àgbàlá níwájú ilé Olúwa , níbẹ̀ sì ni ó ti se ìrúbọ ọrẹ sísun àti ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ó ti ṣe kò lè gba ọrẹ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọ̀rá náà Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì se àsè ní àkókò náà fún ọjọ́ méje àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ àti ìjọ ènìyàn ńlá, àwọn ènìyàn láti Lébò Hámátì títí dé odò Éjíbítì Ní ọjọ́ kẹ́jọ, wọ́n sì pe ìjọ ènìyàn jọ nítorí tí wọ́n pe àpèjẹ ìyà símímọ́ ti orí pẹpẹ fún ọjọ́ méje àti àṣe náà fún ọjọ́ méje sí i Ní ọjọ́ kẹtàlélógún tí oṣù kéje, ó sì rán àwọn ènìyàn padà sí ilé wọn, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú nínú wọn fún ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dáfídì àti Sólómónì, àti fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì Nígbà tí Sólómónì ti parí ilé Olúwa àti ibi ilé ọba, nígbà tí ó sì ti ṣe àṣeyọrí láti gbé jáde gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe nínú ilé Olúwa àti nínú ilé òun tìkálárarẹ̀, Olúwa sì farahàn ní òru ó sì wí pé Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti yàn ibííyí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé fún ẹbọ Nígbà tí mo bá sé ọ̀run kí ó ma báà sí òjò, tàbí láti pàsẹ fún eṣú láti jẹ ilẹ̀ náà run tàbí rán àjàkálẹ̀-àrùn sí àárin àwọn ènìyàn mi, Tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn Nísisinyí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbíyìí Èmi sì ti yàn, èmi sì ti ya ilé yìí sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí orúkọ mi kí ó le wà níbẹ̀ títí láéláé Ní ti bí ìwọ bá rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba rẹ ti ṣe, tí o sì ṣe gbogbo ohun tí mo palásẹ, tí ìwọ sì ṣe àkíyèsí àṣẹ mi láti ọ̀run Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe pẹ̀lú Dáfídì baba rẹ nígbà tí mo bá a dá májẹ̀mu wí pé, ìwọ kò ní fẹ́ ẹnìkan kù láti ṣe alákòóso lórí Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá yípadà tí o sì kọ òfin mi sílẹ̀ àti àṣẹ tí mo ti fi fún yín tí ẹ sì lọ sókè láti lọ sin Ọlọ́run mìíràn tí ẹ sì bọ wọ́n, Nígbà náà ni èmi yóò fa Ísírẹ́lì tu kúrò láti ilẹ̀ mi, èyí tí èmi ti fi fún wọn, èmi yóò sì kọ̀ ilé náà sílẹ̀ èyí tí èmi ti yà sọ́tọ̀ fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ṣe ọ̀rọ̀ òwe, n ó fi ṣe ẹlẹ́yà láàrin gbogbo ènìyàn, Àti ní gbogbo àyíká ilé yìí nísinsinyí, bẹ́ẹ̀ ni yóò di ohun ìtànjẹ gbogbo àwọn tí ó bá sì kọjá níbẹ̀ ni yóò jáláyà, wọn yóò sì wí pé, Kí ni ó dé tí Olúwa fì ṣe irú èyí sí ilẹ̀ yí àti sí ilé yìí Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa sílẹ̀, Ọlọ́run baba wọn ẹni tí ó mú wọn jáde láti Éjíbítì wá, wọ́n sì ti fi ọwọ́ gba Ọlọ́run mìíràn mọ́ra, wọ́n bọ wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyí tí ó fi mú gbogbo ìjàǹbá náà wá sórí wọn   Àwọn Iṣẹ́ Sólómónì Mìíràn Lẹ́yìn ogún ọdún lásìkò ìgbà tí Sólómónì kọ́ ilé Olúwa àti ilé òun fúnrarẹ̀ Sólómónì tún ìlú tí Hírámù ti fi fún un kọ́, ó sì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ níbẹ̀ kí wọn kí ó lè máa gbé nínú ibẹ̀ Nígbà náà Sólómónì lọ sí Hámátì Sóbà ó sì borí rẹ̀ Ó sì tún kọ́ Tádímórì ní ihà àti gbogbo ìlú ìsúra tí ó ti kọ́ ní Hámátì Ó sì tún kọ́ òkè Bẹti Hórónì àti ìsàlẹ̀ Bétì Hórónì gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi, pẹ̀lú ògiri àti pẹ̀lú ìlẹ̀kùn àti ọ̀pá-ìdábùú Àti gẹ́gẹ́ bí Bálátì àti gbogbo ìlú Ìṣúra, àti gbogbo ìlú fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn ẹsin rẹ̀ ohunkóhun tí ó bá yẹ ní kókó ní Jérúsálẹ́mù, ní Lẹ́bánónì àti ní gbogbo àyíká agbégbé tí ó ń darí Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kúrò láti ara àwọn ará Hítì, ará Ámórò, ará Pérísì, ará Hífì àti ará Jébúsì , Èyí ni wí pé, àwọn ọmọ wọn tí ó kù sílé ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò parun àwọn ni Sólómónì bu iṣẹ́ ìrú fún títí di òní yìí Ṣùgbọ́n Solómónì kò mú ọmọ ọ̀dọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún Ísírẹ́lì, wọn jẹ́ ọ̀gágun rẹ̀, olùdarí àwọn oníkẹ̀kẹ́ àti olùdarí kẹ̀kẹ́ Wọ́n sì tún jẹ́ olórí alásẹ fún ọba Sólómónì àádọ́ta ó lé nígba àwọn alákòóso lórí àwọn ènìyàn Sólómónì gbé ọmọbìnrin Fáráò sókè láti ìlú Dáfídì lọ sí ibi tí ó ti kọ́ fún un, nítorí ó wí pé Aya mi kò gbọdọ̀ gbé nínú ilé Dáfídì ọba Ísírẹ́lì nítorí ibi tí àpótí ẹ̀rí Olúwa bá tí wọ̀, ibi mímọ́ ni Lórí pẹpẹ Olúwa tí ó ti kọ́ níwájú ìloro náà, Sólómónì sì rú ẹbọ ọrẹ sísun sí Olúwa , Nípa ìlànà ojojúmọ́ fún ẹbọ rírú tí a pa lásẹ láti ọ̀dọ̀ Mósè wá fún ọjọ́ ìsinmi, oṣù tuntun àti lẹ́rìn mẹ́ta lọ́dún, ní àjọ àkàrà àìwú, ní àjọ ọ̀ṣẹ̀ méje àti àjọ ìpàgọ́ Ní pípamọ́ pẹ̀lú ìlànà baba rẹ̀ Dáfídì, ó sì yan ipa àwọn àlùfáà fún iṣẹ́ wọn àti àwọn ọmọ Léfì láti jẹ́ adarí láti máa yin àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìlànà ojojúmọ́ Ó sì tún yàn àwọn olùsọ́nà nípa pípín sí olúkúlùkù ẹnu ọ̀nà, nítorí èyí ni Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run ti paláṣẹ Wọn kò sì yà kúrò nínú àṣẹ ọba sí àwọn àlùfáà tàbí sí àwọn ọmọ Léfì, sí òràn kọ̀ọ̀kan, àti pẹ̀lú ti ìṣúra Gbogbo iṣẹ́ Sólómónì ni a gbé jáde láti ọjọ́ ìfi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lé lẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ ìparí Bẹ́ẹ̀ ni ilé Olúwa sì parí Nígbà náà ni Sólómónì lọ sí Ésíónì Gébérì àti Élótì àti sí etí òkun Édómù Húrámù sì fi ọ̀kọ̀ ránsẹ́ sì i nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó mòye òkun Èyí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Sólómónì, lọ sí Ófírì wọ́n sì gbé àádọ́ta irinwó tálẹ́ntì wúrà wá, padà èyí tí wọ́n sì mú tọ ọba Sólómónì wá Ọbabìnrin Ṣébà Bẹ Sólómónì Wò Nígbà tí ayaba Ṣébà gbọ́ nípa òkìkí Sólómónì, ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù láti dán-an-wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasíẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Sólómónì ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀ Sólómónì sì dáa lóhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀ kò sì sí èyíkéyìí tí kò lè ṣe àlàyé fún Nígbà tí ayaba Ṣébà rí ọgbọ́n Sólómónì àti pẹ̀lu ilé tí ó ti kọ́, Oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì rẹ̀, àti ìjòkòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti dídúró àwọn ìránṣẹ́ nínú aṣọ wọn, àti àwọn agbọ́tí nínú aṣọ wọn àti ẹbọ ọrẹ sísun tí ó ṣe ní ilé Olúwa , ó sì ní ìdálágara Ó sì wí fún ọba pé, Ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ, òtítọ́ ni Ṣùgbọ́n èmi kò gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́ àyàfi ìgbà tí mó dé ibí tí mo sì ri pẹ̀lú ojú mi Nítòótọ́, kì í tilẹ̀ ṣe ìdàjọ́ ìdajì títóbi ọgbọ́n rẹ ní a sọ fún mi ìwọ ti tàn kọ já òkìkí tí mo gbọ́ Báwo ni inú àwọn ọkùnrin rẹ ìbá ṣe dùn tó! Báwó nínú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí n dúró nígbà gbogbo níwájú rẹ láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ! Ìyìn lóyẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Ísírẹ́lì láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́ Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà talẹ́ntì wúrà Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye Kò sì tíì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣébà fifún ọba Sólómónì Àwọn ènìyàn Húrámù àti àwọn ọkùnrin Sólómónì gbé wúrà wá láti Ófírì, wọ́n sì tún gbé igi álígúmù pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá Ọba sì lo igi álígúmù náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé Olúwa àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun ọ̀nà orin fún àwọn akọrin Kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti rírí ní ilẹ̀ Júdà Ọba Sólómónì fún ayaba Ṣébà ní gbogbo ohun tí ó bèèrè fún àti ohun tí ó wù ú ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀ Ìwọ̀n wúrà tí Sólómónì gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà talẹ́ntì , Láì tíì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Árábíà àti àwọn báálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Sólómonì Ọba Solómónì sì ṣe igba àṣà wúrà lílù ẹgbẹ̀ta àsà tí a fi òlùlù wúrà sí òkànkàn sékélì Ó sì ti ṣe ọ̀ọ́dúnrún kékeré ṣékélì tí a fi òlù lù wúrà, pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún sékélì wúrà nínú àpáta kọ̀kan Ọba sì kó wọn sínú ilé ti igbó Lébánónì Nígbà náà ọba sì ṣe ìtẹ́ pẹ̀lú èyín erin ńlá kan ó sì fi wúrà tó mọ́ bò ó Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, àti pẹ̀lú àpóti ìtìsẹ̀ wúrà kan ni a dè mọ́ ọn Ní ìhá méjèèjì ibi ìjókòó ní ó ní ìropá, pẹ̀lú kìnnìun tí ó dúró lẹ́bàá olúkúlùkù wọn Kìnnìún méjìlá dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́ta, ọ̀kan àti ní ìhà olúkúlùkù àtẹ̀gùn kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti ṣe rí fún ìjọba mìíràn Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solómónì ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò agbo ilé ní ibi igbó Lébánonì ni ó jẹ́ wúrà mímọ́ Kò sì sí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Húrámù ń bojútó Ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin, àti ìnàkí àti ẹyẹ ológe wá Ọba Solómónì sì tóbi nínú ọlá ńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojú rere lọ́dọ̀ Sólómónì láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀ Ní ọdọdún, olúkúlùkù ẹni tí o wá mú ẹ̀bùn ohun èlò wúrà àti fàdákà àti aṣọ ìbora, ìhámọ́ra, àti tùràrí, àti ẹsin àti ìbaka wá Sólómónì sì ní ẹgbàajì ilé fún àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàfà àwọn ẹsin , tí ó ba mọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jérúsálẹ́mù Ó sì jọba lórí gbogbo àwọn ọba láti odò títí dé ilé àwọn ará fìlístínì àti títí ó fi dé agbègbè ti Éjíbítì Ọba sì ṣe fàdákà gẹ́gẹ́ bí ìwọpọ̀ ní Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí òkúta àti igi kédárì ó sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí igi síkámórè ni ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ gígi A sì mú àwọn ẹsin Sólómónì láti ilẹ̀ òkèrè láti Éjíbítì àti láti gbogbo ìlú Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ìjọba Sólómónì, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn Nátanì wòlíì, àti nínú ìsọtẹ́lẹ̀ Áhíjà ará Sílónì àti nínú ìran Ídò, wòlíì tí o kan Jéróbámù ọmọ Nébátì Sólómónì jọba ní Jérúsálẹ́mù lórí gbogbo àwọn Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún Sólómónì sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì baba rẹ̀, Réhóbóámù, ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Ọlọ́run Gbogbo Ìtùnú Pọ́ọ̀lù Àpósítélì Jésù Kírisítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Tímótíù arákùnrin wá, sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọ́ríńtí pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn-mímọ́ tí ó wà ní gbogbo Ákáyà Oore-ọ̀fẹ́ si yín àti àlàáfíà làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jésù Kírísítì Olúwa Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jésù Kírísítì Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa lè máa pẹ̀lú tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá Nítorí pé bí ìjìyà Kírísítì ti sínú ayé wa,, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ pẹ̀lú nípa Kírísítì Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín tàbi bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù làti mú yin ní irú ìfaradá ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́ Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹyin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹyin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú Ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Éṣíà, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́ Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá òun ní àwa gbẹ́kẹ̀ wa lé pé yóò sí máa gbà wá ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, Bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ń fí àdúrà yín ìràn wá lọ́wọ́ Àti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò dúpẹ́ nítorí wa fún oore-ọ̀fẹ́ ojúrere táa rí gbà nípa ìdáhún sí àdúrà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn Nítorí èyí ní ìsògo wá, ẹ̀rí láti inú ọkàn wa pẹ̀lú ìń jérìí wí pé àwa ń gbé ìgbésí ayé tí ó ní tumọ̀ pàápàá jùlọ nínú ìbágbépọ̀ wa pẹ̀lú yín, nínú ìwà mímọ́ àti òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá Kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn ni àwa ń ṣe èyí bí kò ṣe nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Nítorí pé àwa kò kọ̀wé ohun tí èyín kò lè kà mòye rẹ̀ sí yín Mo sì tún ní ìrètí wí pé Gẹ́gẹ́ bí ẹyín pẹ̀lú ti ní ìmọ̀ nípa wa ní apákan, bákan náà ni ẹ ó ní ìmọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ tí ẹ ó sì fi wá yangàn, bí àwa pẹ̀lú yóò ṣe fi yín yangàn ní ọjọ́ Jésù Olúwa Nítorí mo ní ìdánilójú yìí wí pé, mo pinnun láti kọ́kọ́ bẹ̀ yín wò kí ẹ lè jànfààní ìgbà méjì Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìn àjò mi sí Makedóníà àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedóníà àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìn àjò mi sí Jùdíà Nítorí náà nígbà tí èmi ń gbérò bẹ́ẹ̀, èmi há ṣiyèméjì bí Tàbí àwọn ohun tí mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹ́gẹ́ bí ti ará bí, pé kí ó jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ ní àti Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́ Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòótọ́, ọ̀rọ̀ wa fún yín kí í ṣe bẹ́ẹ̀ ni ati bẹ́ẹ̀ kọ́ Nítorí pé Jésù Kírísítì, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí a tí wàásù rẹ̀ láàárin yín nípaṣẹ̀ èmí àti Silífánù àti Tímótíù, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nínú rẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ ní Nítorí tí gbogbo ìlérí Ọlọ́run dí bẹ́ẹ̀ ni nínú Kírísítì Nítorí ìdí èyí ní a ṣe ń wí pé Àmín nípaṣẹ̀ rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run Ǹjẹ́ níṣinṣin yìí, Ọlọ́run ni ó fí ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ pẹ̀lú yín nínú Kírísítì, Òun ni ó ti fi àmì òróró yàn wá, ó sì fí èdìdì rẹ̀ dì wá pẹ̀lú, ó sì tí fi Ẹ̀mí rẹ́ sí wa ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ó ń bọ̀ Mo sì pe Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ọkàn mi pé nítorí àtidá yín sí ní èmi kò ṣe padà sí Kọ́ríńtì Kì í ṣe nítorí tí àwa jẹ gàba lórí ìgbàgbọ́ yín ṣùgbọ́n àwa ń ṣisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú yín fún ayọ̀ yín nítorí nípa ìgbàgbọ́ ni ẹ̀yin dúró sinisin Pọ́ọ̀lù Gbéjà Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Ṣùgbọ́n èmi Pọ́ọ̀lù fúnra mi fi inú tútù àti ìwà pẹ̀lẹ́ Kírísítì bẹ̀ yín, èmi ẹni ìrẹ̀lẹ̀ lójú yín nígbà tí mo wà láàárin yín, ṣùgbọ́n nígbà tí èmi kò sí, mo di ẹni ìgboyà sí yín Ṣùgbọ́n èmi bẹ̀ yín pé nígbà tí mo wà láàárin yín, kí èmi baà lè lo ìgboyà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé náà, eléyìí tí mo ti fọkàn sí láti fi dojúkọ àwọn kan, ti ń fúra sí wa bí ẹni tí ń rìn nípa ti ara Nítorí pé, bí àwa tilẹ̀ rìn nípa ti ara, ṣùgbọ́n àwa kò jagun nípa ti ara Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀ Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbékùn wá sí ìtẹríba fún Kírísítì Àwa sì ti murá tan láti jẹ gbogbo àìgbọ́ràn níyà, nígbà tí ìgbọ́ràn yín bá pé Ẹ̀yin sì ń wo nǹkan gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi hàn lóde Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìgboyà nínú ara rẹ̀, ti Kírísítì ni òun, kí ó tún rò lẹ́ẹ̀kan si pé, bí òun ti jẹ́ ti Kírísítì, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwa pẹ̀lú jẹ́ ti Kírísítì Nítorí bí mo tilẹ̀ ń ṣògo bí ó ti wù mi nítorí agbára, tí Olúwa ti fifún wá fún mímú yn ìdàgbàsókè, dípò fífa yín subú, ojú kí yóò tì mí Kí ó má ṣe dàbí ẹni pé èmi ń fí ìwé kíkọ dẹ́rùbá yín Nítorí wọ́n wí pé, Ìwé rẹ wúwo, wọn sì lágbára ṣùgbọ́n ìrísí rẹ̀ jẹ aláìlera, ọ̀rọ̀ rẹ kò níláárí Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé, irú ẹni tí àwa jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ nípa ìwé kíkọ nígbà tí àwa kò sí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa sì jẹ́ nínú iṣẹ́ pẹ̀lú nígbà ti àwa bá wà Nítorí pé àwa kò dáṣà láti ka ara wa mọ́, tàbí láti fí ara wa wé àwọn mìíràn nínú wọn tí ń yin ara wọn ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn jẹ́ aláìlóye bí wọn ti ń fí ara wọn díwọ̀n ara wọ́n, tí wọ́n sì ń fí ara wọn wé ara wọn Ṣùgbọ́n àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, ṣùgbọ́n nípa ààlà ìwọ̀n tí Ọlọ́run ti pín fún wa, èyí tí ó mú kí ó ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ yín Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìyìn rere Kírísítì Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ elòmiràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọpọ̀ Kí a bà à lè wàásù ìyìn rere ní àwọn ìlú tí ń bẹ níwájú yín, kí a má sì ṣògo nínú ààlà ẹlòmíràn nípa ohun tí ó wà ní àrọ́wọ́tó Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Olúwa Nítorí kì í ṣe ẹni tí ń yin ara rẹ̀ ni ó ní itẹ́wọ́gbà, bí kò ṣe ẹni tí Olúwa bá yìn Pọ́ọ̀lù Àti Àwọn Àósítélì Ẹlẹ́kọ̀ọ́ Èké Mo rò wí pé ẹ ó farada díẹ̀ nínú ìwà òmùgọ̀ mi ṣùgbọ́n ẹ tilẹ̀ ti rí ṣe bẹ́ẹ̀ Nítorí pé èmi ń jówu lórí i yín ní ti owú ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúndíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kírísítì Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Éfà jẹ́ nípaṣẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín sáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajìn fún Kírísítì Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jésù mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á Nítorí mo rò pé èmi kò rẹ̀yìn ní ohunkohun sí àwọn àgbà Àpósítélì Bí mo tilẹ̀ jẹ́ òpè nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe nínú ìmọ̀ Ní ọ̀nàkọnà ni àwa ti fi èyí hàn dájúdájú fún yín nínú ohun gbogbo Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìyìn rere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́ Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbigba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedóníà wá ti mú wá Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀ Ó jẹ́ òtítọ́, Kírísítì tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Ákáyà Nítorí kín ni Nítorí èmi kò fẹ́ràn yín ni bí Ọlọ́run mọ̀ Ṣùgbọ́n ohun ti mo ń ṣe ni èmi yóò sì máa ṣe, kí èmi lè mú ẹ̀fẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fẹ́ ṣẹ̀fẹ̀, pé nínú ohun tí wọ́n ṣògo, kí a lè rí wọn gẹ́gẹ́ bí àwa Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn èkè Àpósítélì àwọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa wọ́n dà di Àpósítélì Kírísítì Kì í sì í ṣe ohun ìyanu nítorí Sátanì, tìkáraarẹ̀ ń pa ara rẹ̀ dà bí ańgẹ́lì ìmọ́lẹ̀ Nítorí náà kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá pa ara wọn dà bí àwọn ìrànṣẹ́ òdodo ìgbẹ́yìn àwọn ẹni tí yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn Mo sì tún wí pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé òmùgọ̀ ni mí ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ẹ gbà mí bí òmùgọ̀ kí èmi lè gbé ara mi ga díẹ̀ Ohun tí èmi ń sọ, èmi kò sọ ọ́ nípa ti Olúwa, ṣùgbọ́n bí òmùgọ̀ nínú ìgbẹ́kẹ̀lé ìṣògo yìí Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ni ó ń ṣògo nípa ti ara, èmi ó ṣògo pẹ̀lú Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkáraayín jẹ́ ọlọgbọ́n Nítorí ẹ̀yin faradà á bí ẹnìkan bá sọ yín dí òǹdè, bí ẹnìkan bá jẹ́ yín run, bí ẹnìkan bá gbà lọ́wọ́ yín, bí ẹnìkan bá gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹnìkan bá gbá yín lójú Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera! Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú Hébérù ni wọ́n bí Bẹ́ẹ̀ ni èmi Ísírẹ́lì ni wọ́n bí Bẹ́ẹ̀ ni èmi Irú ọmọ Ábúráhámù ní òun bí Bẹ́ẹ̀ ni èmi Iránṣẹ́ Kírísítì ni wọ́n bí Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbákùúgbà, ní ti fífẹ́rẹ̀ kú nígbà púpọ̀ Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín kan lọ́wọ́ àwọn Júù Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú Ní ìrìnàjò nígbákùúgbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní ihà, nínú ewu lójú òkun, nínú ewu láàárin àwọn èké arákùnrin Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́-òru nígbákùúgbà, nínú ebi àti òrùgbẹ, nínú ààwẹ̀ nígbákùúgbà, nínú òtútù àti ìhòòhò Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọ́ jọ tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ Ta ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi Ọlọ́run àti Baba Olúwa wá Jésù Kírísítì, ẹni tí ó jẹ́ olùbùkún jùlọ láéláé mọ̀ pé èmi kò ṣèké Ní Dámásíkù, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ọba Árétà fí ẹgbẹ́ ogun ká ìlú àwọn ara Dámásíkù mọ́, ó ń fẹ́ mi láti mú Láti ojú fèrèsé nínú agbọ̀n ni a sì ti sọ̀ mí kalẹ̀ lẹ́yìn odi, tí mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ Ìṣípayá Pọ́ọ̀lù Àti Ẹ̀gún Tí Ń Bẹ Lára Rẹ̀ Èmi kò lè sàì sògo bí kò tilẹ̀ ve àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípayá ti Olúwa fihàn mí Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kírísítì ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yin, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀ tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀ Ọlọ́run mọ̀ a gbé irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ lọ sí ọ̀run kẹta Bẹ́ẹ̀ ni èmi mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, yálà ní ara ni, tàbí kúrò nínú ara ni, èmi kò mọ̀ Ọlọ́run mọ̀ Pé a gbé e lọ sókè sí Párádísè, tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a kò sì lè sọ, tí kò tọ́ fún ènìyàn láti máa sọ Nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni èmi ó máa ṣògo ṣùgbọ́n nípa ti èmi tìkáraami èmi kì yóò ṣògo, bí kò ṣe nínú àìlera mi Nítorí pé bi èmi tilẹ̀ ń fẹ́ máa ṣògo, èmi kì yóò jẹ́ òmùgọ̀ nítorí pé èmi yóò sọ òtítọ́ ṣùgbọ́n mo kọ̀, kí ẹnikẹ́ni máa bà à fi mí pè ju ohun tí ó rí tí èmi jẹ́ lọ, tàbí ju èyí tí ó gbọ́ lẹ́nu mi Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsípayá, kí èmi má ba à gbé ara mi ga rékọjá, a sì ti fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ìránṣẹ́ Sátanì láti pọ́n mi lójú, kí èmi má bá a gbéraga rékọjá Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi Òun sì wí fún mi pé, Oore ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fí ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kírísítì lè máa gbé inú mi Nítorí náà èmi ní inú dídùn nínú àìlera gbogbo, nínú ẹ̀gàn gbogbo, nínú àìní gbogbo, nínú inúníbíni gbogbo, nínú wàhálà gbogbo nítorí Kírísítì Nítorí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára Mo di òmùgọ̀ nípa ṣíṣògo ẹ̀yin ní ó fí ipá mú mi ṣe é nítorí tí ó tọ́ tí ẹ bá yìn mí nítorí tí èmi kò rẹ̀yìn lóhunkóhun sí àwọn àgbà Àpósítélì bí èmi kò tilẹ̀ jámọ́ nǹkan kan Ohun kan tí ó ṣe àmì àpósítélì, iṣẹ́ ìyanu and iṣẹ́ agbára ní won ṣe ní àárin yín pẹ̀lú sùúrù tó ga Nítorí nínú kín ni ohun tí ẹ̀yin ṣe rẹ̀yìn sí ìjọ mìíràn, bí kò ṣe ní ti pé èmi fúnra mi kó jẹ́ oníyọnú fún yín Ẹ dárí àṣìṣe yìí jì mí Kíyèsí i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò se àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́ bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọpọ̀, ó há tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí Ṣùgbọ́n ó dára bẹ́ẹ̀ tí èmi kò dẹ́rúbà yín ṣùgbọ́n bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, èmi ń fí ọwọ́ ẹ̀rọ̀ mú yín Èmi há rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi Mo bẹ Títù, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀ Títù há rẹ́ yín jẹ bí Nípa ẹ̀mi kan náà kọ́ àwa rìn bí Ọ̀nà kan náà kọ́ àwa tọ̀ bí Ẹ̀yin há rò pé àwa ń sọ nǹkan wọ̀nyí láti gbèjà ara wa níwájú yín bí Ní iwájú Ọlọ́run ni àwa ń ṣọrọ nínú Kírísítì ṣùgbọ́n àwa ń ṣe ohun gbogbo, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láti gbé yín ró ni Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé, nígbà tí mo bá dé, èmi kì yóò bá yín gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí mo fẹ́, àti pé ẹ̀yin yóò sì rí mi gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ẹ̀yin kò fẹ́ Kí ìjà, owú-jíjẹ, ìbínú, ìpínyà, ìsọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, ìjírọ̀sọ̀, ìfẹẹ́gẹ̀, ìrúkèrúdò, má bà à wà Àti nígbà tí mo bá sì padà dé, kí Ọlọ́run mí má bà à rẹ̀ mí sílẹ̀ lójú yín, àti kí èmi má bà à sọkún nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó tí ṣẹ̀ náà tí kò sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà èérí, àgbérè, àti wọ̀bìà tí wọ́n ti hù Àwọn Ìkìlọ̀ ìkẹyìn Èyí ni ó dí ìgbà kẹta tí èmi ń tọ̀ yín wá Ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó fí ìdí ọ̀rọ̀ gbogbo múlẹ̀ Mo ti sọ fún yín ṣáájú, mo sì ń sọ fún yín tẹ́lẹ̀, bí ẹni pé mo wà pẹ̀lú yín nígbà kejì, àti bí èmi kò ti sí lọ́dọ̀ yín ní ìsinsin yìí, mo kọ̀wé sí àwọn tí ó ti ṣẹ̀ náà, àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíran, pé bí mo bá tún padà wá, èmi kì yóò dá wọn sí Níwọ̀n bí ẹ̀yin tí ń wá àmì Kírísítì ti ń sọ̀rọ̀ nínú mi, ẹni tí kì í ṣe àìlera sí yin, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ agbára nínú yín Nítorí pé a kàn án mọ́ àgbélébùú nípa àìlera, ṣùgbọ́n òun wà láàyè nípa agbára Ọlọ́run Nítorí àwa pẹ̀lú já sí aláìlera nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run sí yín Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́ ẹ máa dán ara yín wò Tàbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ ara yín pé Jésù Kírísítì wá nínú yín Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù Ṣùgbọ́n mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, àwa kì í ṣe àwọn tí a tanù Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù Nítorí àwa kò lè ṣe ohun kan lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe fún òtítọ́ Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yín sì jẹ́ alágbára èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín Ìdí nìyí mo ṣe kọ̀wé àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá dé kí èmi má ba à lo ìkanra ní lílo àṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa ti fifún mí, láti mú dàgbàsókè, kì í ṣe láti fà yín subú Ní àkótan, ará ó dì gbòóṣe, ẹ ṣe àtúnse ọ̀nà yín, ẹ tújúká, ẹ jẹ́ onínúkan, ẹ máa wà ní àlàáfíà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín Gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ kí yín Oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa, àti ìfẹ́ Ọlọ́run, àti ìdàpọ̀ ti Èmí Mímọ́, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín Ìdáríjì Fún Ẹlẹ́ṣẹ̀ Nítorí náà mo tí pínnú nínú ara mí pé, èmi kì yóò tún fí ìbànújẹ́ tọ̀ yin wá Nítorí pé bí èmi bá mú inú yín bàjẹ́, ǹjẹ́ ta ni ẹni ti ìbá mú inú mí dùn ní àkókò tí inú mi bá bàjẹ́ bí kò ṣe ẹni tí mo ti ba nínú jẹ́ Èmi sì kọ̀wé bí mo tí kọ sí yín pé, nígbà tí mo bá sì de, kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ti ìbá mú mi ní ayọ̀ nítorí tí mo ní ìgbẹkẹlé nínú gbogbo yín, wí pé ẹ̀yin yóò jẹ́ alábápín ayọ̀ mi Nítorí pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà àti ìrora ọkàn mí ni mo ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ omijé kọ̀wé sí yín kì í ṣe nítorí kí a lè bà yín nínú jẹ́, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin bá a lè mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹyin fúnra yín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́ n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fí jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀ Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìdánilójú ìfẹ́ yín hàn sí Olúwa rẹ̀ Ìdí tí mo ṣe kọ̀wé, kí èmi baà lè rí ẹ̀rí dìmú nípa ìgbọ́ràn yín nínú ohun gbogbo Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá dáríjín ẹnikẹ́ni, èmí fi jì pẹ̀lú Èmi ti dárìjìn níwájú Kírítí nítorí yín Kí Sàtánì má baà rẹ́ wa jẹ Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀ Ṣùgbọ́n nígbá ti mo dé Tíróà láti wàásù iyinrere Kírísitì, tí mo sì ríi wí pé Olúwa ti sílẹ̀kùn fún mi, Síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kan mi, nítorí tí èmi kò rí Títù arákùnrin mi níbẹ̀ Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedóníà, Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kírísítì, tí a sì ń fi òórùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo Nítorí òórùn dídùn Kírísítì ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn ikú sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè Ta ni ó há si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí Nítorí àwa kò dàbí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí ń fí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣòwò jẹun ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ inú àwa ń sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọ́run nínú Kírísítì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá Ògo Tó Wà Nínú Májẹ̀mu Túntún Àwa há tún bẹ̀rẹ̀ làti máa yín ara wá bí Tàbí àwa ha ń fẹ́ ìwé ìyìn sọ́dọ̀ yín, tàbí làti ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ẹlòmíràn tí ń ṣe Ẹ̀yin fúnara yín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà Ẹ̀yin sì ń fi hàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kírísítì ni yín, kì í ṣe èyí tí a si fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè kì í ṣe nínú wàláà okútà bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ènìyàn Irú ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ yìí ni àwa ní nípaṣẹ̀ Kírísítì sọ́dọ̀ Ọlọ́run Kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé làti ọ̀dọ̀ àwa tìkárawa ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà Ẹni tí ó mú wa tó bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú titun kì í ṣe ní ti ìwé-àkọọ́lẹ̀ nítorí ìwé a máa pani, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ni dí ààyè Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mósè nítorí ògo ojú rẹ̀ Yóò há ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù Nítorí pé bi iṣẹ́ìrànṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìrànṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ Nítorí pé bí èyí ti ń kójá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fí ìgbóyà púpọ̀ sọ̀rọ̀ Kì í sì í ṣe bí Mósè, ẹni tí ó fí ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Ísríẹ́lì má baà lè tẹjú mọ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ Ṣùgbọ́n ojú-inú wọn fọ́ nítorí pé títí fí di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mu láéláé, ìbòjú kan náà sì wà láìká kúrò nítorí pé nínú Kírísítì ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbákùúgbà ti a bá ń ka Mósè, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kan wọn Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà níbì tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnirà gbé wà Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjijì, a sì ń pawádà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí Ìṣúra Nínú Ohun-Èlò Amọ̀ Nitorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí bí àwa ti rí ní iṣẹ́-ìránṣẹ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí a ti fi àánú gbà, àárẹ̀ kò mú wá Ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣùgbọ́n nípa fífí òtítọ́ hàn, àwa ń fí ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run Ṣùgbọ́n báyìí, bí iyinrere wa bá sí farasin, ó farasin fún àwọn tí ó ń ṣègbé Nínú àwọn ẹni tí Ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìyìn rere Kírísítì tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àworán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn Nítórí àwa kò wàásù àwa tìkárawa, bí kò se Kírísítì Jésù Olúwa àwa tikarawa sì jẹ́ ẹrú yín nítorí Jésù Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, Kí ìmọ́lẹ̀ ó mọ́lẹ̀ láti inú òkùnkùn jáde, òun ní ó ti ń mọ́lẹ̀ lọ́kan wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jésù Kírísítì Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò àìmọ́, kí ọlá ńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá a ń dàámú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀ a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jésù Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jésù hàn pẹ̀lú lará wa Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fí àwa tí ó wà láàyè fún ikú nítorí Jésù, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín Bí a ti kọ́, Èmi ìgbàgbọ́, nítorí náà ni Èmi ṣe sọ pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà a tún gbàgbọ́ àti nítorí náà ni àwa sì ṣe ń sọ Àwa mọ̀ pé, ẹni tí o jí Jésù Olúwa dìde yóò sì jí wa dìde pẹ̀lú nípa Jésù, yóò sì mú wa wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú yín Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọpẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, ṣíbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di túntún lójoojúmọ́ Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ kíún yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayè tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa Níwọ̀n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé Ibùgbé Wa Ọ̀run Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòòhò Nítorí àwa tí ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa yóò jẹ́ aláìwọsọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè baà lè gbé ara kíkú mì Ǹjẹ́ ẹni tí ó ti pèṣè wa fún nǹkan yìí ni Ọlọ́run, ẹni tí o sì ti fi Ẹ̀mí fún wa pẹ̀lú ni ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ń bọ̀ Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rírí Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa Nítorí náà àwa ń dù ú, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọ́dọ̀ fí ara hán níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kírísítì kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i ti ṣe nígbà tí ó wà nínú ara ìbáà ṣe rere tàbí búburú Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà ṣùgbọ́n a ń fí wá hàn fún Ọlọ́run mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hán ní ọkàn yín pẹ̀lú Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lodé ara kì í ṣe ní ọkàn Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni tàbí bí iyè wá bá sí pépé, fún yín ni Nítorí ifẹ́ Kírísítì ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láàyè má sì ṣe wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde Nítorí náà láti ìṣinṣin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́ bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kírísítì nípa ti ara, ṣùgbọ́n níṣinṣin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́ Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kírísítì, ó di ẹ̀dá titun ohun àtijọ́ ti kọjá lọ kíyèsí i, ohun titun ti dé Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì típaṣẹ̀ Jésù Kírísítì bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kírísítì, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́ Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kírísítì, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín àwa ń bẹ̀ yín nípò Kírísítì, Ẹ bá Ọlọ́run làjà, Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀ Àwọn Wàhálà Pọ́ọ̀lù Gẹ́gẹ́ bí alábáṣiṣẹ́ pọ̀ nínú Ọlọ́run, ǹjẹ́, àwa ń rọ̀ yín kí ẹ má ṣe gba oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lásán Nítorí o wí pé, Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ, àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́ Èmi wí fún ọ, nísínsín yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísínsín yìí ní ni ọjọ́ ìgbàlà Àwa kò sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan si ọ̀nà ẹnikẹ́ni, ki iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa má ṣe di ìsọ̀rọ̀ òdì sí Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fí ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà, nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìṣan, nínú ìgbààwẹ̀ Nínú ìwà mímọ̀, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mi Mímọ̀, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apa òsì Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìyìn rere bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a já sí ólóòótọ́, bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a si wà láàyè bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá, bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo bí talákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀ bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo Ẹ̀yin ará Kọ́ríńtì, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa payá sí yín A kò ni yín lára nítorí wa, ṣùgbọ́n a ni yín lára nítorí ìfẹ́ ọkàn ẹ̀yin fúnra yín Ní sísán padà, ní ọ̀nà tí ó dára, ẹ̀yin náà, ẹ ṣí ọkàn yín payá pẹ̀lú Ẹ má ṣe fí àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́ nítorí idápọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo Ìdápọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kírísítì ní pẹ̀lú Bélíàlì Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́ Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà Nítorí ẹ̀yin ní tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run alààyè gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé, Èmi á gbé inú wọn, èmi o sì máa rìn láàárin wọn èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàárin wọn, kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀, ni Olúwa wí Ki ẹ má ṣe fi ọwọ kan ohun àìmọ́ Èmi ó sì gbà yín Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín, Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi! ní Olúwa Olódùmarè wí Ayọ̀ Pọ́ọ̀lù Nítorí náà, ẹyin olufẹ́, bí a ti ní àwọn ìlérí wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí, kí a sọ ìwà mímọ́ dí pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run Ẹ gbà wá tọkàntọkàn a kò fi ibi ṣe ẹnikẹ́ni, a kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ Èmi kò sọ èyí làti dá a yín lẹ́bí nítorí mo tí wí ṣáájú pé, ẹ̀yin wà nínú ọkàn wa kí a lè jùmọ̀ kú, àti kí a lè jùmọ̀ wà láàyè Mo ní ìgbóyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀ ìṣògo mí lórí yín pọ̀ mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedóníà, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Títù dé Kì í sì i ṣe nípa dídé rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nípa ìtùnú náà pẹ̀lú tí ẹ ti tù ú nínú, nígbà tí ó ròyìn fún wa ìfẹ́ àtọkàn wá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìtara yín fún mi bẹ́ẹ̀ ní mo sì túbọ̀ yọ̀ Nítorí pé, bí mo tilẹ̀ ba inú yín jẹ́ nípa ìwé tí mo kọ èmi kò kábámọ̀ mọ́, bí mo tilẹ̀ ti kábámọ̀ tẹ́lẹ̀ rí nítorí tí mo wòye pé ìwé mi mú yín banújẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀ Èmi yọ̀ nísinsin yìí, kì í ṣe nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́, ṣùgbọ́n nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́ sí ìrònúpìwàdà nítorí ti a mú inú yín bàjẹ́ bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ̀yin má ṣe ti ipasẹ̀ wa pàdánù ní ohunkóhun Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run a máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwadà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú Kíyèsí i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúrá-ṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ńkọ́ ìbànújẹ́ ńkọ́, ìpayà ńkọ́, ìfojúsọnà ńkọ́, ìtara ńkọ́, ìjẹ́ni-níyà ńkọ́ Nínú ohun àmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ tí kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe ohun búburú náà tàbí nítorí ẹni ti a fi ohun búburú náà ṣe, ṣùgbọ́n kí àníyàn yín nítorí wá lè farahàn níwájú Ọlọ́run Nítorí náà, a tí fí ìtùnú yín tù wá nínú Àti nínú ìtùnú wa, a yọ̀ gidigidi nítorí pé Títù ní ayọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ gbogbo yín ni a ti tu ẹ̀mí rẹ̀ lára Bí mo tilẹ̀ ti lérí ohunkóhun fún ún nítorí yín, a kò dójú tì mí ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwa ti sọ ohun gbogbo fún yín ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìlérí wá níwájú Títù sì já sí òtítọ́ Ọkàn rẹ̀ sì fà gidigidi sí yín, bí òun ti ń ránti ìgbọ́ràn gbogbo yín, bí ẹ ti fi ìbẹ̀rù àti ìwárìrì tẹ́wọ́gbà á Mo yọ̀ nítorí pé ní ohun gbogbo, mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín Ọ̀rọ̀ Ìyànjú Lórí Ìfifúnni Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedóníà Bí ó ti jẹ́ pé dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti ìdégóńgó àìní wọn ti kún à kún wọ́ sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́ Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnra wọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run Tó bẹ́ẹ̀ tí àwa fi gba Títù níyànjú pé, bí ó tí bẹ̀rẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì parí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí nínú yín pẹ̀lú Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti pọ̀ lóhun gbogbo, ní ìgbàgbọ́, àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀, àti nínú iṣẹ́ ìyìnrere gbogbo, àti ní ìfẹ́ yín sí wa, ẹ rí i wí pé ẹ̀yin pọ̀ sí i nínú ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí pẹ̀lú Kì í ṣe nípa àṣẹ ni mo fi ń sọ ọ́, ṣùgbọ́n kí a lé rí ìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín pẹ̀lú, nípa iṣẹ́ ìyìnrere ẹlòmírán Nítorí ẹ̀yin mọ oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì, pé bí òun ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ rí ṣùgbọ́n nítorí yín ó di talákà kí a lè sọ yín di ọlọ́rọ̀ nípa àìní rẹ̀ Àti nínú èyí ni mo fí ìmọ̀ràn mi fún yín nítorí èyí ṣe àǹfààní fún yín, ẹ̀yin tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ níwọ̀n ọdún tí ó kọjá, kì í ṣe láti ṣe nǹkan, ṣùgbọ́n láti fẹ́ pẹ̀lú Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ parí ṣíṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú kí ó baà lè ṣe pé, bí ìmúra tẹ́lẹ̀ fún ṣiṣe ti wà, bẹ́ẹ̀ ni kí ìparí sì wà láti inú agbára yín Nítorí bí ìmúra tẹ́lẹ̀ bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní Nítorí èmi kò fẹ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín Ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba, Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àní ṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú baà lè ṣe déédé àìní yín kí ìmúdọ́gba baà lè wà Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, Ẹni tí o kó pọ̀ jù, kò ní nǹkan lé tayọ ẹni tí o kò kéré jù kò ṣe aláìnító Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fi ìtara àníyàn kan náà yìí sí ọkàn Títù fún yín Nítorí kì í ṣe pé òun gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa nìkan ni ṣùgbọ́n bí òun ti ní ìtara púpọ̀, òun tìkárarẹ̀ tọ̀ yín wá, fúnra rẹ̀ Àwa ti rán arákùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, ìyìn ẹni tí ó wà nínú ìyìn rere yíká gbogbo ìjọ Kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ẹni tí a tí yàn wá pẹ̀lú láti ọ̀dọ̀ ìjọ láti máa bá wa rìn kiri nínú ọ̀ràn oore-ọ̀fẹ́ yìí, tí àwa ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀ fún ògo Olúwa àti ìmúra tẹ́lẹ̀ wa Àwa ń yẹra fún èyí, kí ẹnikẹ́ni má baà rí wí sí wa ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí tí àwa pín Àwa ń gbérò ohun rere, kì í ṣe níwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n níwájú ènìyàn pẹ̀lú Àwa sì ti rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí àwa rí dájú nígbà púpọ̀ pé ó ní ìtara nínú ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ní isínsnyìí ni ìtara rẹ̀ túbọ pọ̀ sí i nípa ìfọkàntàn ńlá tí ó ní sí yín Bí ẹnikẹ́ni bá béèrè ẹni tí Títù jẹ́, ẹlẹ́gbẹ́ àti olùbáṣiṣẹ́ mi ni, nítorí yín tàbí ní ti àwọn arákùnrin wa ni ẹnikẹ́ni ń bèèrè, ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n jẹ́, àti ògo Kírísítì Nítorí náà ẹ fí ẹ̀rí ìfẹ́ yín hàn wọ́n níwájú ìjọ, àti ìṣògo wa nítorí yín Ìfúrúgbìn Tọkàntọkàn Nísinsinyìí, nípa ti ìpínfúnni fún àwọn ènìyàn mímọ́, kò tún yẹ mọ́ fún mi láti kọ̀wé sí yin ju bẹ́ẹ̀ lọ Nítorí mo mọ ìmúra tẹ́lẹ̀ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedóníà nítorí yín, pé, Ákáyà ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè Ṣùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀ Kí ó má baà jẹ́ pé, bí àwọn nínú ara Makedóníà bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúra sílẹ̀, ojú a sì tì wá kì í ṣe ẹ̀yin, ní ti ìgbẹ́kẹ̀lé yìí Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ̀ bí ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti ìfipágbà Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kínún, kínún ni yóò ká ẹní tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọ̀kàn rẹ̀ kì í ṣe àfìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọ́dọ̀ má ṣe nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé Ó tí fọ́nká ó ti fifún àwọn talákà Òdodo rẹ̀ dúró láéláé Ǹjẹ́ ẹni tí ń fí irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa Nítorí iṣẹ́-ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn-mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run Nítorí ìdúró yin lábẹ́ ìdánwò iṣẹ́-ìsìn yìí, wọn yóò yin Ọlọ́run lógo fún ìgbọ́ràn yín ní gbígba ìyìn rere Kírísítì àti nípa ìlawọ́ ìdánwò yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn Nígbà tí àwọn tìkárawọn pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ fún un yín ń ṣe àfẹ́rí yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti ń bẹ nínú yín Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí aláìlèfẹnusọ ẹ̀bùn rẹ̀! Alàgbà, Sì àyànfẹ́ obìnrin-ọlọ́lá àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ ní òtítọ́, kì í sì í ṣe èmí nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ pẹ̀lú nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí Oore-ọ̀fẹ́, àánú, àti àlààáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Kírísítì, Ọmọ Baba, yóò wà pẹ̀lú nínú òtítọ́ àti nínú ìfẹ́ Mo yọ̀ gidigidi pé mo rí nínú àwọn ọmọ rẹ tí ń rìn nínú òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí Baba ti pá àṣẹ fún wa Ǹjẹ́ nísinsin yìí, mo bẹ̀ ọ́, obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe bí ẹni pé èmi ń kọ̀wé òfin tuntun kan sí ọ, bí kò ṣe èyí ti àwa tí ní ní àtèkèkọ́ṣe, pé kí àwá fẹ́ràn ara wa Èyí sì ni ìfẹ́, pé, kí àwa máa rin nípa òfin rẹ̀, èyí ni òfin náà, àní bí ẹ ti gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé, kí ẹ̀yin rìn nínú rẹ̀ Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jésù Kírísítì wá nínú ara Èyí ni ẹlẹ̀tàn àti Aṣòdì sí Kírísítì Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò si dúró nínú ẹ̀kọ́ Kírísítì, kò mọ Ọlọ́run Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó mọ Baba àti Ọmọ Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mu ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé, kí ẹ má sì ṣe kí i kú àbọ̀ Nítorí ẹni tí ó bá kí i kú àbọ̀, ó ní ọwọ́ nínú iṣẹ́ búburú rẹ̀ Bí mo ti lẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alabapin pẹ̀lú yín, síbẹ̀èmi kò fẹ́ lo ìwé-ìkọ́wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ àyànfẹ́ kí ọ Ìdájọ́ Lẹ́yìn ikú Áhábù, Móábù sọ̀tẹ̀ sí Ísírẹ́lì Nísinsìn yìí Áhásáyà ti ṣubú láàrin fèrèsé láti òkè yàrá rẹ̀ tí ó wà ní Ṣamáríà, ó sì fi ara pa Ó sì rán oníṣẹ́, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Bálísébúbù, òrìṣà Ékírónì, bóyá èmi ó lè rí ìwòsàn ìfarapa yìí Ṣùgbọ́n ańgẹ́lì Olúwa wí fún Èlíjà ará Tíṣíbì pé, Lọ sókè kí o lọ bá ìránṣẹ́ ọba Ṣámáríà kí o sì bèèrè lọ́wọ́ wọn, Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni ẹ̀yìn fi jáde lọ ṣèwádìí lọ́wọ́ Bálísébúbù òrìṣà Ékírónì Nítorí náà ohun tí Olúwa sọ ni èyí Ìwọ kò ní kúrò lórí ìbùsùn tí o dúbúlẹ̀ lé Dájúdájú ìwọ yóò kú!  Bẹ́ẹ̀ ni Èlíjà lọ Nígbà tí ìránṣẹ́ náà padà sí ọ̀dọ̀ ọba, ó béèrè ní ọwọ́ wọn pé, Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi tètè padà wá Wọ́n dáhùn pé, Ọkùnrin kan wá láti pàdé wa, ó sì wí fún wa pé, Ẹ padà sí ọ̀dọ̀ ọba tí ó rán an yín kí ẹ sì wí fún un pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni o fi ń rán àwọn ènìyàn láti lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Bálísébúbù, òrìṣà Ékírónì Nítorí náà ìwọ kò ní fi orí ibùsùn tí ìwọ dúbúlẹ̀ lé sílẹ̀ Láìsí àníàní ìwọ yóò kú!   Ọba béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Irú ọkùnrin wo ni ó wá pàdé yín, tí ó sì sọ irú èyí fún un yín Wọ́n dáhùn pé, Ó jẹ́ ọkùnrin tí ó wọ ẹ̀wù onírun lára pẹ̀lú ọ̀já àmùrè aláwọ́ tí ó gbà yíká ìbàdí rẹ̀ Ọba sì wí pé, Èlíjà ará Tíṣíbì ni Ó sì rán balógun pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ogun àádọ́ta rẹ̀ Balógun náà sì gòkè tọ Èlíjà lọ, ẹni tí ó jókòó ní orí òkè, wọ́n sì wí fún un pé, Ènìyàn Ọlọ́run, ọba wí pé, Sọ̀kalẹ̀ wá!  Èlíjà sì dá balógun lóhùn pé, Tí ó bá jẹ́ wí pé ènìyàn Ọlọ́run ni mí, kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti òkè ọ̀run wá kí ó sì jó ìwọ àti àwọn àádọ́ta ọkùnrin rẹ! Nígbà náà iná náà sì sọ̀kalẹ̀ wá láti òkè ọ̀run ó sì jó balógun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Ọba sì tún rán balógun àádọ́ta pẹ̀lú àwọn ènìyàn àádọ́ta rẹ̀ sí Èlíjà Balógun náà sì wí fún un pé, Èniyàn Ọlọ́run, èyí ni ohun tí ọba ṣọ, Ṣọ̀kalẹ̀ kánkán!  Tí Èmi bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run, Èlíjà sì dáhùn, Ǹjẹ́ kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run kí ó sì jó ọ run àti àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ! Nígbà náà iná Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó o run pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ọba tún rán balógun kẹta pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ọkùnrin Balógun ẹ̀ẹ̀kẹ́ta lọ sí òkè, ó sì kúnlẹ̀ lórí orókún rẹ̀ níwájú Èlíjà Ènìyàn Ọlọ́run, Ó sì bẹ̀bẹ̀ pé, Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ẹ̀mí mi àti ẹ̀mí àwọn àádọ́ta ìránṣẹ́ rẹ wọ̀nyí ṣọ̀wọ́n ní ojú rẹ! Wò ó, iná ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run láti jó àwọn balógun méjì àràádọ́ta àkọ́kọ́ pẹ̀lú àràádọ́ta wọn Ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí ní ojúrere fún ẹ̀mí mi! Ańgẹ́lì Olúwa sọ fún Èlíjà pé, Ṣọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni Èlíjà dìde ó sì ṣọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba Ó sọ fún ọba pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì fún ọ láti pè ni ìwọ fi rán ìránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Bálísébúbù, òrìṣà Ékírónì láti lọ ṣe ìwádìí Nítorí pé o ṣe èyí, ìwọ kò níi dìde lórí ibùsùn tí o dúbúlẹ̀ lé láìsí àní àní ìwọ yóò kú! Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí Èlíjà ti sọ Nítorí Áhásáyà kò ní ọmọ, Jéhórámù jẹ ọba ní ọdún kejì tí Jéhórámù ọmọ Jèhósáfátì ọba Júdà Àti ní ti gbogbo àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Áhásáyà, àti ohun tí ó ṣe, ṣe a kò ha kọ wọ́n sí inú ìwé ọdọọdún ti àwọn ọba Ísírẹ́lì A Pa Ìdílé Áhábù Nísinsìn yìí, Áhábù sì ní àádọ́rin ọmọkùnrin ní ìdílé rẹ̀ ní Ṣamáríà Bẹ́ẹ̀ ni, Jéhù kọ lẹ́tà, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Samáríà sí àwọn oníṣẹ́ Jésérẹ́lì, sí àwọn àgbààgbà àti sí àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Áhábù Ó wí pé, Ní kété tí lẹ́tà bá ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ ọ̀gá a rẹ wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹṣin, ìlú olódi kan pẹ̀lú ohun ìjà, yan èyí tí ó dára àti èyí tí ó níye jùlọ nínú àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ, kí o sì gbé e lé orí ilé baba a rẹ̀ Nígbà náà, kí o sì jà fún, ilé ọ̀gá à rẹ Ṣùgbọ́n dẹ́rùbà wọ́n, wọ́n sì wí pé, Tí ọba méjì kò bá le kojú ìjà sí i, báwo ni a ṣẹ le è ṣeé Bẹ́ẹ̀ ni olùpínfúnni a fún, olórí ìlú ńlá, àwọn àgbààgbà àti àwọn olùtọ́jú náà rán iṣẹ́ yìí sí Jéhù Ìránṣẹ́ rẹ ni àwa jẹ́ pẹ̀lú, àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá sọ Àwa kì yóò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ọba Ìwọ ṣe ohunkóhun tí o rò pé ó dára jù Nígbà náà, Jéhù kọ lẹ́tà kejì síwọn, wí pé, Tí ìwọ bá wà ní ìhà tèmi, tí o sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, mú orí àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi ní Jésérẹ́lì ní ìwòyí ọ̀la Nísinsìn yìí, àwọn ọmọ aládé bìnrin ti ọba, àádọ́rin wọn sì wà pẹ̀lú àwọn adarí ọkùnrin ní ìlú àwọn tí wọ́n ń bọ́ wọn Nígbà tí ìwé náà dé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí mú gbogbo àwọn ọmọ aládé bìnrin, wọ́n sì pa gbogbo àádọ́rin wọn Wọ́n gbé orí i wọn sí inú apẹ̀rẹ̀, wọ́n fi ránṣẹ́ sí Jéhù ní Jésérẹ́lì Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé, ó sọ fún Jéhù, Wọ́n ti gbé orí àwọn ọmọ aládé bìnrin náà wá Nígbà náà Jéhù pàṣẹ, Kó wọn sí ẹ̀bú méjì sí àbáwọlé ìlẹ̀kùn ìlú ńlá títí di òwúrọ̀ Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Jéhù jáde lọ Ó dúró níwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, Ẹ̀yin jẹ́ aláìjẹ̀bi Èmi ni mo dìtẹ̀ sí ọ̀gá mi, tí mo sì pa á, ṣùgbọ́n ta ni ó pa gbogbo àwọn wọ̀nyí! Nígbà yìí, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí Olúwa ti sọ sí ilé Áhábù tí yóò kùnà Olúwa ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí nípaṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù pa gbogbo ẹni tí ó kù ní ilé Áhábù, pẹ̀lú pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ tímọ́-tímọ́ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, láì ku ẹni tí ó yọ nínú ewu fún un Jéhù jáde lọ, ó sì lọ sí ọ̀kánkán Ṣamáríà Ní Bẹti-Ékédì tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ó pàdé díẹ̀ lára àwọn ìbátan Áhásáyà ọba Júdà, ó sì béèrè, Ta ni ẹ̀yin ń ṣe Wọ́n wí pé, Àwa jẹ́ ìbátan Áhásáyà, àwa sì ti wá láti kí ìdílé ọba àti ti mọ̀mọ́ ayaba Mú wọn láàyè! ó pàṣẹ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ẹ̀bá kọ̀nga Bẹti-Ékédì, ọkùnrin méjìlélógójì Kò sì fi ẹnìkan sílẹ̀ láìkù Lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò níbẹ̀, ó wá sórí Jéhónádábù ọmọ Rékábù tí ó wà ní ọ̀nà rẹ̀ láti lọ bá a Jéhù kí i, ó sì wí pé, Ṣé ìwọ wà ní ìbárẹ́ pẹ̀lú mi, bí èmi ti wa pẹ̀lú ù rẹ Èmi wà, Jéhónádábù dáhùn Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Jéhù wí, fún mi ní ọwọ́ ọ̀ rẹ Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe pẹ̀lú, Jéhù sì ràn án ọ́ lọ́wọ́ sókè sí inú kẹ̀kẹ́ Jéhù wí pé, Wá pẹ̀lú ù mi kí o sì rí ìtara mi fún Olúwa Nígbà náà ó jẹ́ kí ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀ Nígbà tí Jéhù wá sí Ṣamáríà, ó pa gbogbo àwọn tí a fi kalẹ̀ ní ìdílé Áhábù ó pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ sí Èlíjà Nígbà náà, Jéhù kó gbogbo àwọn ènìyàn jọ, ó sì wí fún wọn pé, Áhábù sin Báálì díẹ̀ ṣùgbọ́n Jéhù yóò sìn ín púpọ̀ Nísinsìn yìí, ẹ pe gbogbo àwọn wòlíì Báálì jọ, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àlùfáà rẹ̀ Rí i wí pé, kò sí nǹkankan tí ó ń sọnù nítorí ẹ̀mi yóò rú ẹbọ ńlá fún Báálì Ẹnìkíní tí ó bá kọ̀ láti wá, kò ní wà láàyè mọ́ Ṣùgbọ́n Jéhù fi ẹ̀tàn ṣe é, kí ó lè pa àwọn òjíṣẹ́ Báálì run Jéhù wí pé, ẹ pe àpẹ̀jọ ní wòyí ọ̀la fún Báálì Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kéde rẹ Nígbà náà, ó rán ọ̀rọ̀ káàkiri Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Báálì sì wá kò sí ẹnìkan tí ó dúró lẹ́yìn Wọ́n kún ilé tí a kọ́ fún òrìṣà títí tí ó fi kún láti ìkángun èkíní títí dé èkejì Jéhù sì sọ fún olùṣọ́ pé, Kí ó mú aṣọ ìgúnwà wá fún gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Báálì Bẹ́ẹ̀ ni ó mú aṣọ ìgúnwà jáde wá fún wọn Nígbà náà, Jéhù àti Jéhónádábù ọmọ Rékábù lọ sí inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì Jéhù sì wí fún àwọn òjíṣẹ́ Báálì pé, Wò ó yíká, kí o sì rí i pé kò sí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kankan pẹ̀lú yín níbí—kìkì òjíṣẹ́ Báálì Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọ inú ilé lọ láti lọ rú ẹbọ àti ọrẹ sísun Nísinsìn yìí Jéhù ti rán ọgọ́rin ọkùnrin sí ìta pẹ̀lú ìkìlọ̀ yìí Tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọkùnrin tí mo ń gbé sí ọwọ́ yín ó sá lọ, yóò jẹ́ ẹ̀mí yín fún ẹ̀mí ì rẹ Ní kété tí Jéhù ti parí ṣíṣe ọrẹ sísun, ó pàṣẹ fún àwọn olùṣọ́ àti àwọn ìjòyè Wọlé lọ, kí o sì pa wọ́n Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó sálọ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà Àwọn olùṣọ́ àti ìjòyè ju ara wọn síta, wọ́n sì wọ inú ojúbọ ti ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì Wọ́n gbé òkúta bíbọ náà jáde láti inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì, wọ́n sì jó o Wọ́n fọ́ òkúta bíbọ ti Báálì náà túútúú, wọ́n sì ya ilé òrìṣà Báálì bolẹ̀ Àwọn ènìyàn sì ń lò ó fún ilé ìgbẹ́ títí di ọjọ́ òní Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù pa sísin Báálì run ní Ísírẹ́lì Bí ó ti wù kí ó rí, kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó ṣokùnfà Ísírẹ́lì láti dá—ti sísin ẹgbọ̀rọ̀ màlúù wúrà ní Bétélì àti Dánì Olúwa sì sọ fún Jéhù pé, Nítorí ìwọ ti ṣe dáradára ní ṣíṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú mi, tí o sì ti ṣe sí ilé Áhábù gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn mi, àwọn ọmọ ọ̀ rẹ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì títí dé ìran kẹrin Ṣíbẹ̀ Jéhù kò ṣe pẹ̀lẹ́ láti pa òfin Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì mọ́ pẹ̀lú tọkàntọkàn Òun kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù èyí tí ó ṣokùnfà Ísírẹ́lì láti dá Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Olúwa ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dín iye Ísírẹ́lì kù Hásáélì fi agbára tẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo agbégbé wọn Ìlà-oòrùn ti Jọ́dánì ni gbogbo ilẹ̀ ti Gílíádì láti Áróérì, tí ó wà létí Ánónì Gọ́ọ́jì láti ìhà Gílíádì sí Básánì Fún ti òmìíràn ti iṣẹ́ ìjọba Jéhù, gbogbo ohun tí ó ṣe, gbogbo àṣeyọrí rẹ̀, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì Jéhù sin mi pẹ̀lú baba a rẹ̀, a sì sin ín sí Ṣamáríà Jéhóáhásì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Àkókò tí Jéhù fi jọba lórí Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà jẹ́ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n Ataláyàyà Àti Jóásì Nígbà tí Ataláyàyà ìyá Áhásáyà rí i wí pé ọmọ rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀ṣíwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba náà run Ṣùgbọ́n Jéhóṣébà ọmọbìnrin ọba Jéhórámù àti arábìnrin Áhásáyà, mú Jóásì ọmọ Áhásáyà, ó sì jí i lọ kúrò láàárin àwọn ọmọ aládé bìnrin ti ọba náà, tí ó kù díẹ̀ kí a pa Ó gbé òhun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù láti fi pamọ́ kúrò fún Ataláyà Bẹ́ẹ̀ ni a kò pa á Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú olùtọ́jú ní ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataláyà fi jọba lórí ilẹ̀ náà Ní ọdún kéje, Jéhóíádà ránṣẹ́ sí àwọn olóórí ní ọrọrún àwọn balógun àti àwọn olùṣọ́, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa Ó ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, ó sì fi wọ́n sí abẹ́ ìbúra nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa Níbẹ̀ ni ó fi ọmọkùnrin ọba hàn wọ́n Ó pàṣẹ fún wọn, wí pé, Ìwọ tí ó wà nínú àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ta tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi—ìdámẹ́ta yín fún síṣọ́ ààfin ọba Ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn Ṣúrì, àti ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn ní ẹ̀yìn olùṣọ́, tí ó yípadà ní síṣọ́ ilé tí a kọ́, Àti ẹ̀yin tí ó wà ní ẹgbẹ́ kejì yóòkù tí kì í lọ ibi iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi gbogbo ni kí ó ṣọ́ ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọba Ẹ mú ibùjókòó yín yí ọba ká, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ọgbà yìí gbúdọ̀ kú Ẹ dúró súnmọ́ ọba ní ibikíbi tí ó bá lọ Olórí àwọn ọrọọrún ṣe gẹ́gẹ́ bí Jéhóíádà àlùfáà ti paà láṣẹ́ Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ àwọn tí ó ń lọ sí iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jéhóíádà àlùfáà Nígbà náà, ó fún àwọn olórí ní àwọn ọ̀kọ̀ àti àwọn apata tí ó ti jẹ́ ti ọba Dáfídì tí ó sì wà nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa Àwọn olùṣọ́, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sì dúró ṣinṣin yìí ọba ká—lẹ́báá pẹpẹ àti ilé ìhà gúsù sí ìhà àríwá ilé tí a kọ́ fun Olúwa náà Jéhóíádà mú ọmọkùnrin ọba jáde, ó sì gbé adé náà lé e ó fún un ní ẹ̀dà májẹ̀mú, wọ́n sì kéde ọba rẹ̀ Wọ́n fi àmì òróró yàn án, àwọn ènìyàn pa àtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe, Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn Nígbà tí Ataláyà gbọ́ ariwo tí àwọn olùṣọ́ àti àwọn ènìyàn ń pa, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa Ó wò ó, níbẹ̀ ni ọba, tí ó dúró lẹ́bàá òpó, gẹ́gẹ́ bí àṣà ti rí Àwọn ìjòyè àti àwọn afọ̀npè wà ní ẹ̀bá ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilé náà sì ń yọ̀ wọ́n sì ń fọ̀npè pẹ̀lú Nígbà náà Ataláyà fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya Ó sì kégbe pé, Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀! Jéhóíádà àlùfáà pàṣẹ fún olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, ta ni ó wà ní ìkáwọ́ ọ̀wọ́ ogun Mú u jáde láàrin àwọn ẹgbẹ́ ogun yìí kí o sì fi sí ipa idà ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé Nítorí àlùfáà ti sọ, A kò gbọdọ̀ pa á nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi agbára mú un bí ó ti dé ibi tí àwọn ẹṣin tí ń wọ ilẹ̀ ààfin àti níbẹ̀ ni a ti pa á Nígbà náà ni Jéhóíádà dá májẹ̀mú láàrin Olúwa àti ọba àti àwọn ènìyàn tí yóò jẹ́ ènìyàn Olúwa Ó dá májẹ̀mú láàrin ọba àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà lọ sí ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì wọ́n sì ya á bolẹ̀ Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti òrìṣà sí wẹ́wẹ́ Wọ́n sì pa Mátanì àlùfáà Báálì níwájú àwọn pẹpẹ Nígbà náà, Jéhóíádà àlùfáà náà sì yan àwọn olùṣọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa Ó mú pẹ̀lú u rẹ̀ àwọn olórí ọ̀rọọrún àti gbogbo balógun àti àwọn olùṣọ́ àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti lápapọ̀, wọ́n mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé tí a kọ́ fún Olúwa Wọ́n sì wọ inú ààfin lọ, wọ́n sì wọlé nípa ìlẹ̀kùn ti àwọn olùṣọ́ Ọba sì mú àyè rẹ̀ ní orí ìtẹ́ ọba Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, pẹ̀lú ìlú ńlá náà sì dákẹ́ jẹ́ẹ́ Nítorí a pa Ataláyà pẹ̀lú idà náà ní ààfin Jóásì jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀ Jóásì Tún Ilé Tí A Kọ́ Fún Ní ọdún keje tí Jéhù, Jóásì di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ogójì ọdún Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Síbíyà Ó wá láti Beeriṣébà Jóásì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa ní gbogbo ọdún tí Jéhóíádà àlùfáà fi àsẹ fún un Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn ní ìdí Àwọn ènìyàn sì tẹ̀ṣíwájú láti máa rú ẹbọ àti sísun tùràrí níbẹ̀ Jóásì sọ fún àwọn àlùfáà pé, Gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa owó tí a gbà ní ìgbà kíka àwọn ènìyàn ìlú, owó tí a gbà láti ọwọ́ olúkúlùkù bí wọ́n ti ṣe jẹ́ ẹ̀yà àti owó tí ó ti ọkàn olúkúlùkù wá tí a múwá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa Jẹ́ kí gbogbo àlùfáà gba owó náà lọ́wọ́ ọ̀kan nínú àwọn akápò Kí a sì lò ó fún túntún ohunkóhun tí ó bá bàjẹ́ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹtàlélógún ọba Jóásì, àwọn àlùfáà kò ì tí ì tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe Nígbà náà, ọba Jóásì pe Jéhóíádà àlùfáà àti àwọn àlùfáà yóòkù, ó sì bi wọ́n, pé Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tún ìbàjẹ́ tí a ṣe sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe Ẹ má ṣe gba owó mọ́ lọ́wọ́ àwọn afowópamọ́, ṣùgbọ́n ẹ gbé e kalẹ̀ fún túntun ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe Àwọn àlùfáà faramọ́ pé wọn kò ní gba owó kankan mọ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sì ni, wọn kò sì ní tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe mọ́ fún ra wọn Jéhóíádà àlùfáà mú àpótí kan, ó sì lu ihò sí ìdérí rẹ̀ Ó gbé e sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ní apá ọ̀tún bí ẹnìkan ti wọlé tí a kọ́ fún Olúwa Àwọn àlùfáà tí ó ṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé fi sínú àpótí náà gbogbo owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ti rí wí pé owó púpọ̀ wà nínú àpótí, akọ̀wé àti olórí àlùfáà yóò wá, wọ́n á ka owó náà tí wọ́n ti mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa Wọn a sì kó o sínú àwọn àpò Nígbà tí wọ́n bá ti pinnu iye rẹ̀, wọn a kó owó náà fún àwọn tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa Pẹ̀lú u rẹ̀, wọ́n sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa Àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùkọ́lé Àwọn ilé ńlá àti àwọn agékúta Wọ́n ra igi gẹdú àti òkúta tí wọ́n tọ́jú fún titun ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe Wọ́n tún ohun gbogbo tí wọ́n ná fún títún tẹ́ḿpílì ṣe Owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa kò jẹ́ níná fún ṣíṣe òpó fàdákà, àlùmágàjí fìtílà, àwokòtò, ipè, ohun èlò wúrà tàbí ohun èlò fàdákà kan fún ilé tí a kọ́ fún Olúwa A sì san án fún àwọn ọkùnrin tí ó ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n ń tọ́jú ilé tí a kọ́ fún Olúwa Wọn kò sì bá àwọn ọkùnrin náà sírò, ní ọwọ́ ẹni tí wọ́n fún ní owó láti san fún àwọn òṣìṣẹ́ Torí wọ́n ṣe é pẹ̀lú òdodo tí ó pé Owó láti ibi ọrẹ ẹ̀bi àti ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ ní a kò mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa ó jẹ́ ti àwọn àlùfáà Ní déédéé àkókò yìí, Hásáélì ọba Ṣíríà gòkè lọ láti dojúkọ Gátì àti láti fi agbára mú un Nígbà náà, ó yípadà láti dójukọ Jérúsálẹ́mù Ṣùgbọ́n Jóásì ọba Júdà mú gbogbo ohun mímọ́ tí a gbé ka iwájú tí a yà sọ́tọ̀ nípasẹ̀ baba rẹ̀—Jéhósáfátì, Jéhórámù àti Áhásáyà, àwọn ọba Júdà, àti àwọn ẹ̀bùn tí òun tìkálára rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ àti gbogbo wúrà, tí ó rí nínú ibi ìfowópamọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti níti ààfin ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Hásáélì ọba Ṣíríà, tí ó sì fa padà kúrò ní Jérúsálẹ́mù Pẹ̀lú ìyókù ìṣe Jóásì, àti ohun gbogbo tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ sí i wọ́n sì lù ú pa ní Bẹti-Mílò ní ọ̀nà sí Ṣílà Àwọn oníṣẹ́ tí ó pa á jẹ́ Jósábádì ọmọ Ṣíméátì àti Jéhósábádì ọmọ Ṣómérì Ó kú, wọ́n sì sin-ín pẹ̀lú baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dáfídì Ámásáyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Jéhóáhásì Ọba Ísírẹ́lì Ní ọdún kẹtàlélógún ti Jóásì ọmọ ọba Áhásáyà ti Júdà, Jéhóáhásì ọmọ Jéhù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà Ó sì jọba fún ọdún mẹ́tadínlógún Ó ṣe búburú níwájú Olúwa nípa títẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá, kò sì yípadà kúrò nínú wọn Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti fún ìgbà pípẹ́, ó fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ agbára ọba Hásáélì ọba Ṣíríà àti Bẹni-Hádádì ọmọ rẹ̀ Nígbà náà Jéhóáhásì kígbe ó wá ojú rere Olúwa , Olúwa sì tẹ́tí sí i Nítorí ó rí bí ọba Ṣíríà ti ń ni Ísírẹ́lì lára gidigidi Olúwa pèsè Olùgbàlà fún Ísírẹ́lì, wọ́n sì sá kúrò lọ́wọ́ agbára Ṣíríà Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé nínú ilé ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀ Ṣùgbọ́n wọn kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jéróbóámù, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá Wọ́n tẹ̀ṣíwájú nínú rẹ̀ pẹ̀lú òpó Áṣérà dúró síbẹ̀ ní Ṣamáríà Kò sí ohùn kan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ti ọmọ ogun Jéhóáhásì àyàfi àádọ́ta ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, kẹ̀kẹ́ mẹ́wàá, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀, nítorí ọba Ṣíríà ti pa ìyókù run, ó sì ṣe wọ́n bí eruku nígbà pípa ọkà Fún ti ìyókù ìṣe Jéhóáhásì fún ìgbà, tí ó fi jọba, gbogbo ohun tí ó ṣe àti àṣeyọrí rẹ̀ ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì Jéhóáhásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ A sì sin ín sí Samáríà, Jéhóásì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Jóásì ọba Júdà, Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà ó sì jọba fún ọdún mẹ́rìndínlógún Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa , kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì èyí tí ó ti ti Ísírẹ́lì láti fà Ó sì tẹ̀síwájú nínú wọn Fún ti ìyókù iṣẹ́ Jéhóásì fún ìgbà tí ó fi jọba, gbogbo ohun tí ó ṣe, pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀ pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Ámásáyà ọba Júdà, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì Jéhóásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀ Jéróbóámù sì rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́ A sin Jéhóásì sí Samáríà pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì Nísinsìn yìí, Èlíṣà ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn, lọ́wọ́ èyí tí ó sì kú Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì lọ láti lọ wò ó, ó sì ṣunkún lórí rẹ̀ Baba mi!, Baba mi! Ó ṣunkún Àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin Ísírẹ́lì ! Èlíṣà wí pé, Mú ọrun kan àti àwọn ọfà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ Mú ọrun ní ọwọ́ rẹ Ó wí fún ọba Ísírẹ́lì Nígbà tí ó ti mú u, Èlíṣà mú ọwọ́ rẹ̀ lé ọwọ́ ọba Ṣí fèrèsé apá ìlà oòrùn, ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣéé Ta á! Èlíṣà wí, ó sì ta á Ọfà ìṣẹ́gun Olúwa ọfà ìṣẹ́gun lórí Ṣíríà! Èlíṣà kéde Ìwọ yóò pa àwọn ará Ṣíríà run pátapáta ní Áfékì Nígbà náà ó wí pé, Mú àwọn ọfà náà, ọba sì mú wọn Èlíṣà wí fún un pé, Lu ilẹ̀ Ó lù ú lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹẹ̀marùn-ún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹfà Nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Ṣíríà àti pa á run pátapáta ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta péré Èlíṣà kú a sì sin ín Ẹgbẹ́ Àwọn ará Móábù máa ń wọ orílẹ̀ èdè ní gbogbo àmọ́dún Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Èlíṣà Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Èlíṣà, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀ Hásáélì ọba Ṣíríà ni Ísírẹ́lì lára ní gbogbo àkókò tí Jéhóáhásì fi jọba Ṣùgbọ́n Olúwa ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀ Hásáélì ọba Ṣíríà kú, Bẹni-Hádádì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Nígbà náà, Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì gbà padà kúrò lọ́wọ́ Bẹni-Hádádì ọmọ Hásáélì àwọn ìlú tí ó ti gbà nínú ogun látọ̀dọ̀ baba rẹ̀ Jéhóáhásì Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta, Jéhóásì ṣẹ́gun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó gba ìlú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà Ámásáyà Ọba Júdà Ní ọdún kejì tí Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì ọba Ísírẹ́lì, Ámásáyà ọmọ Jóásì ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba Ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Jéhóádínì ó wá láti Jérúsálẹ́mù Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa , ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i Dáfídì baba a rẹ̀ tí ṣe Nínú ohun gbogbo, ó tẹ́lé àpẹrẹ baba a rẹ̀ Jóásì Àwọn ibi gíga bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí i kúrò Àwọn ènìyàn sì tẹ̀ṣíwájú láti rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀ Lẹ́yìn tí ó ti fi ọwọ́ gbá ìjọba rẹ̀ mú gbọin-gbọin, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n ti pa baba a rẹ̀ ọba Síbẹ̀ kò pa ọmọ àwọn apànìyàn náà Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú ìwé òfin Mósè níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé A kì yóò pa baba nítorí àwọn ọmọ, tàbí àwọn ọmọ nítorí àwọn baba olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ Òun ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ará Édómù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ iyọ̀, ó sì fi agbára mú Ṣélà nínú ogun, tí ó ń pè é ní Jókítélì, orúkọ tí ó ní títí di òní Nígbà náà, Ámásáyà rán àwọn ìránṣẹ́ sí Jóásì ọmọ Jéhóáhásì ọmọ Jéhù ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú ìpèlẹ́jọ́ Wá, í bá mi lójúkorojú Ṣùgbọ́n Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì fèsì sí Ámásáyà ọba Júdà Òṣùṣù kan ní Lébánónì rán iṣẹ́ sí Kédárì ní Lébánónì, Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó Nígbà náà ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin tinú ìgbẹ́ ní Lébánónì wá pẹ̀lú ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ òṣùṣú náà mọ́lẹ̀ Ìwọ ti ṣẹ́gun Édómù pẹ̀lú, ṣùgbọ́n, nísinsìn yìí ìwọ ṣe ìgbéraga Ògo nínú ìṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n dúró nílé! Kí ni ó dé tí o fi ń wá wàhálà tí o sì fa ìṣubú rẹ àti ti Júdà pẹ̀lú Bí ó ti wù kí ó rí Ámásíà kò ní tẹ́tí, bẹ́ẹ̀ ni Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì sì dojúkọ ọ́ Òun àti Ámásáyà ọba Júdà kọjú sí ara wọn ní Bẹti-Ṣéméṣì ní Júdà A kó ipa ọ̀nà Júdà nípasẹ̀ Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn ọkùnrin sì sálọ sí ilé e rẹ̀ Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Ámásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóásì, ọmọ Áhásáyà ní Bẹti-Ṣéméṣì Nígbà náà, Jéhóásì lọ sí Jérúsálẹ́mù, ó sì lọ wó odi Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Éfúráímù sí ibi igun ìlẹ̀kùn Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀ta ẹsẹ̀ bàtà Ó mú gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun tí ó rí nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti níbi ìfowópamọ́ sí nínú ààfin ọba Ó mú àwọn ìdógò, ó sì dá wọn padà sí Ṣamáríà Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jéhóásì, gbogbo ohun tí ó ṣe pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀, pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Ámásáyà ọba Júdà, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì Jéhóásì sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín sí Ṣamáríà pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì Jéróbóámù ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ámásáyà ọmọ Jóásì ọba Júdà gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀dógún lẹ́yìn ikú Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì ọba Ísírẹ́lì Fún ti ìyókù iṣẹ́ rẹ̀ nígbà ìjọba Ámásáyà, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà Wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jérúsálẹ́mù, ó sì sálọ sí Lákísì, ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e sí Lákísì, wọ́n sì pa á síbẹ̀ Wọ́n gbé e padà pẹ̀lú ẹṣin, a sì sin ín sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, ní ìlú ńlá ti Dáfídì Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn Júdà mú Ásáríyà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún Wọ́n sì ṣe é ní ọba ní ìrọ́pò baba rẹ̀ Ámásáyà Òun ni ẹni tí ó tún Élátì kọ́, ó sì dá a padà sí Júdà lẹ́yìn tí Ámásáyà ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ Ní ọdún kẹẹ̀dógún tí Ámásáyà ọmọ Jóásì ọba Júdà, Jéróbóámù ọmọ Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì di ọba ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún ọ̀kànlélógójì ọdún Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì Èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá Òun ni ẹni tí ó ti dá àwọn ààlà Ísírẹ́lì padà láti Lebo-Hámátì sí òkú aginjù Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Jónà ọmọ Ámítaì, wòlíì láti Gátì Héférì Olúwa ti rí bí olúkúlùkù yálà ẹrú tàbí òmìnira, ti ń jìyà gidigidi kò sì sí ẹnìkan tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ Láti ìgbà tí Olúwa kò ti wí pé òhun yóò bu àbùkù lu orúkọ Ísírẹ́lì láti abẹ́ ọ̀run Ó gbà wọ́n là, lọ́wọ́ Jéróbóámù ọmọ Jéhóásì Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jéróbóámù, gbogbo ohun tí ó ṣe àti gbogbo àwọn àṣeyọrí ológun rẹ̀ àti bí ó ṣe gbà padà fún Ísírẹ́lì lápapọ̀ Dámásíkù àti Hámátì, tí ó ti jẹ́ ní Yáúdì, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì Jéróbóámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àwọn ọba Ísírẹ́lì Ṣekaríyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ásáríyà Ọba Júdà Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n tí Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Ásáríyà ọmọ Ámásáyà ọba Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rindínlógún nígbà tí o di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìléláàdọ́ta Orúkọ ìyá a rẹ̀ a má a jẹ́ Jékólíà ó wá láti Jérúsálẹ́mù Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa , gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ámásáyà ti ṣe Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn kúrò Àwọn ènìyàn náà tẹ̀ṣíwájú láti máa rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀ Olúwa sì kọlu ọba náà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀, títí di ọjọ́ tí ó kú, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀tọ̀ Jótamì, ọmọ ọba sì tọ́jú ààfin, ó sì ń darí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Ásáríyà, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà Ásáríyà sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀ A sì sin ín sí ẹ̀bá wọn ní ìlú ńlá ti Dáfídì Jótamì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ní ọdún kejìdínlógójì Ásáríyà ọba Júdà Ṣakaríà ọmọ Jéróbóámù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún oṣù mẹ́fà Ó ṣe búburú lójú Olúwa , gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ tí ṣe Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá Ṣálúmù ọmọ Jábésì dìtẹ̀ sí Ṣakaríà Ó dojúkọ ọ́ níwájú àwọn ènìyàn, ó sì pa á, ó sì jọba dípò rẹ̀ Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Ṣakaríà Wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ fún Jéhù jẹ́ ìmúṣẹ Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì títí dé ìran kẹrin Ṣálúmù ọmọ Jábésì di ọba ní ọdún kọkàndínlógójì Ùsáyà ọba Júdà, ó sì jọba ní Ṣamáríà fún oṣù kan Nígbà náà Ménáhémù ọmọ Gádì lọ láti Tírísà sí Ṣamáríà Ó dojúkọ Ṣalúmù ọmọ Jábésì ní Samáríà, ó pa á ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ṣalúmù, àti ìdìtẹ̀ tí ó dì, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì Ní ìgbà tí Ménáhémù ń jáde bọ̀ láti Tíríṣà, ó dojúkọ Tífíṣà àti gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìlú ńlá àti agbègbè rẹ̀, Nítorí wọn kọ̀ láti sí ẹnu ibodè Ó yọ Tífsà kúrò lẹ́nu iṣẹ́, ó sì la inú gbogbo àwọn obìnrin aboyún Ní ọdún kọkàndínlógójì ti Ásáríyà ọba Júdà, Ménáhémù ọmọ Gádì di ọba Ísírẹ́lì, ó sì jọba ní Samáríà fún ọdún mẹ́wàá Ó ṣe búburú lójú Olúwa , ní gbogbo ìjọba rẹ̀ Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá Nígbà náà, Púlù ọba Ásíríà, gbógun ti ilẹ̀ náà, Ménáhémù sì fún un ní ẹgbẹ̀rin talẹ́ńtì fàdákà láti fi gba àtìlẹyìn rẹ̀ àti láti fún ìdúró tirẹ̀ lágbára lórí ìjọba Ménáhémù fi agbára gba owó náà lọ́wọ́ Ísírẹ́lì Gbogbo ọkùnrin ọlọ́lá ní láti dá àádọ́ta ṣékélì fàdákà láti fún ọba Áṣíríà Bẹ́ẹ̀ ni ọba Áṣíríà padà sẹ́yìn, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà mọ́ Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Ménáhémù, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé ọba Ísírẹ́lì Ménáhémù sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ Pékáhíà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ní ọdún kẹẹ̀dógún Ásáríyà ọba Júdà, Pékáhíà ọmọ Ménáhémù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún ọdún méjì Pékáhíà ṣe búburú lójú Olúwa Kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó fa Ísírẹ́lì láti dá Ọ̀kan lára àwọn olórí ìjòyè rẹ̀ Pékà ọmọ Remalíà, dìtẹ̀ síi Ó mú àádọ́ta àwọn ọkùnrin ti àwọn ará Gílíádì pẹ̀lú u rẹ̀ Ó pa Pékáhíà pẹ̀lú Árígóbù àti Áríè ní Kítadélì ti ààfin ọba ní Ṣamáríà Bẹ́ẹ̀ ni Pékà pa Pékáhíà, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Pékáhíà, gbogbo ohun tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì Ní ọdún kejìléláàdọ́ta Ásáríyà ọba Júdà, Pékà ọmọ Rèmálíà di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà Ó sì jọba fún ogún ọdún Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa , kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó fa Ísírẹ́lì láti dá Ní ìgbà Pékà ọba Ísírẹ́lì, Tígílátì Pílésérì ọba Ásíríà wá, ó sì mú Íjónì, Abeli-Bẹti-Máákà, Jánóà, Kédéṣì àti Hásórì Ó gba Gíléádì àti Gálílì pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Náftalì Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Ásíríyà Nígbà náà, Hóséà ọmọ Álíyà, dìtẹ̀ sí Pékà ọmọ Remalíyà Ó dojúkọ ọ́, ó sì pa á, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ogún ọdún Jótamù ọmọ Ùsáyà Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Pékà, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì Ní ọdún keje Pékà ọmọ Remalíà ọba Ísírẹ́lì, Jótamù ọmọ Ùsáyà ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógún Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Jérúṣà ọmọbìnrin Ṣádókù Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí bàbá a rẹ̀ Ùsáyà ti ṣe Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn kúrò Àwọn ènìyàn tẹ̀ṣíwájú láti rú ẹbọ àti láti sun tùràrí níbẹ̀ Jótamù tún ìlẹ̀kùn gíga tó ń kọ́ ní ti ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jótamù, àti ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà Jótamù sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ A sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dáfídì, ìlú ńlá ti baba rẹ̀ Áhásì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ìbẹ̀rẹ̀ Ìjọba Áhásì Lórí Júdà Ní ọdún kẹtàdínlógún Pẹ́kà ọmọ Remálíà, Áhásì ọmọ Jótamù ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ síi jọba Ẹni ogún ọdún ni Áhásì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ó sì jọba ọdún mẹ́rìndínlógún ní Jérúsálẹ́mù, kò si ṣe èyí tí ó tọ́ lójú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba rẹ̀ Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísíráẹ́lì, nítòótọ́, ó sì mú kí ọmọ rẹ̀ ó kọjá láàrin iná, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ ìrírà àwọn aláìkọlà, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísíráẹ́lì Ó sì rúbọ, ó sì ṣun tùràrí ní àwọn ibi gíga, àti lórí àwọn òkè kéékèèkéé àti lábẹ́ gbogbo igi tútù Nígbà náà ni Résínì ọba Ṣíríà àti Pẹ́kà ọmọ Rèmálíà ọba Ísíráẹ́lì gòkè wá sí Jérúsálẹ́mù láti jagun wọ́n dó ti Áhásì, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀ Ní àkókò náà, Résínì Ọba Ṣíríà gba Élátì padà fún Ṣíríà, ó sì lé àwọn ènìyàn Júdà kúrò ní Élátì àwọn ará Ṣíríà sì wá sí Élíátì, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí Áhásì sì rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ Tigilati-Pílésérì ọba Ásíríà wí pé, Ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, àti ọmọ rẹ gòkè wá, kí o sì gbà mi lọ́wọ́ ọba Síríà, àti lọ́wọ́ ọba Ísírẹ́lì tí ó díde sí mi Áhásì sì mú fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé Olúwa , àti nínú ìṣúrà ilé ọba, ó sì rán an sí ọba Ásíríà ní ọrẹ Ọba Ásíríà sì gbọ́ tirẹ̀ nítórí ọba Ásíríà gòkè wá sí Dámásíkù, ó sì kó o, ó sì mú un ní ìgbékùn lọ sí Kírì, ó sì pa Résínì Ọba sì lọ sí Dámásíkù láti pàdé Tigilati-Pílésérì, ọba Ásíríà, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Dámásíkù Áhásì ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Úráyà àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀ Úráyà àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Áhásì ọba fi ránṣẹ́ síi láti Dámásíkù bẹ́ẹ̀ ni Úráyà àlùfàá ṣe é dé ìpadàbọ̀ Áhásì ọba láti Dámásíkù Nígbà tí ọba sì ti Dámásíkù dé, ọba sì rí pẹpẹ náà ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rúbọ lórí rẹ̀ Ó sì ṣun ẹbọ ọrẹ-ṣíṣun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun-mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n èjẹ̀ ọrẹ-àlàáfíà rẹ̀ sí ará pẹpẹ náà Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú Olúwa kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárin méjì pẹpẹ náà, àti ilé Olúwa , ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà Áhásì ọba sì pàṣẹ fún Úráyà àlùfáà, wí pé, Lórí pẹpẹ ńlá náà ni kó o máa ṣun ọrẹ-ṣíṣun òròwúrọ̀ àti ọrẹ-jijẹ alaalẹ́, àti ẹbọ ṣíṣun ti ọba, àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, pẹ̀lú ọrẹ ṣíṣun tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọrẹ jíjẹ wọn, àti ọrẹ ohun mímu wọn kí o sì wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ ọrẹ-sísun náà lórí rẹ̀, àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ mìíràn ṣùgbọ́n ní ti pẹpẹ idẹ náà èmi ó máa gbèrò ohun tí èmi ó fi ṣe Báyìí ni Úráyà àlùfáà ṣe, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Áhásì ọba pa láṣẹ Áhásì ọba sì gé igi-ìpílẹ̀ àwọn àgbédúró náà, ó sí agbada náà kúrò lára wọn ó sì gbé agbada nlá náà kalẹ̀ kúrò lára àwọn màlúù idẹ tí ń bẹ lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbé e ka ilẹ̀ tí a fi òkúta tẹ́ Ibi ààbò fún ọjọ́ ìsinmi tí a kọ́ nínú ilé náà, àti ọ̀nà ìjáde sí òde ọba, ni ó yípadà kúrò ní ilé Olúwa nítorí ọba Ásíríà Àti ìyókù ìṣe Áhásì tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà Áhásì sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dáfídì Heṣekáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Hóséà Ọba Tí Ó Gbẹ̀yìn Ní Ísírẹ́lì Ní ọdún kejìlá ọba Áhásì ará Júdà, Hóséà ọmọ Élà jẹ ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà, ó sì jẹ fún ọdún mẹsàn án Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa , ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i ti ọba Ísírẹ́lì ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ Ṣálámánesérì ọba Áṣíríà wá sókè láti mú Hóséà, ẹni tí ó ti jẹ fún Ṣálámánésérì ó sì ti san owó òde fún un Ṣùgbọ́n ọba Ásíríà ríi wí pé Hóséà jẹ́ ọlọ́tẹ̀, nítorí ó ti rán ońsẹ́ sọ́dọ̀ ọba Éjíbítì, kò sì san owó òde mọ́ fún ọba Áṣíríà, gẹ́gẹ́ bí o ti máa ń ṣe ní ọdọdún Nígbà náà ọba Áṣírìa fi agbára mú-ún, ó sì fi sínú túbú Ọba Ásíríà gòkè wá sí gbogbo ibi ilé náà, ó sì lọ sí Samáríà, ó sì dúró tìí fún ọdún mẹ́ta Ní ọdún kẹsàn-án ti Hóṣéà, ọba Áṣíríà mú Ṣamáríà ó sì kó Ísírẹ́lì lọ sí Áṣíríà Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ní Hálà, ní Gósánì ní ọ̀dọ̀ Hábónì àti ní ìlú àwọn ará Médáì Gbogbo eléyìí ṣẹlẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti dẹ́sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde ní Éjíbítì lábẹ́ agbára Fáráò ọba Éjíbítì Wọ́n sin ọlọ́run mìíràn Wọn si tẹ̀lé ìwà orílẹ èdè tí Olúwa ti gbá kúrò níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà ti ọba Ísírẹ́lì tí ó ti paláṣẹ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun ìríra sí Olúwa Ọlọ́run wọn kọ́ láti ilé ìsọ́ sí ìlú tí a dábòbò, wọ́n kọ́ ilé gíga fún ara wọn ní gbogbo ìlú wọn Wọ́n sì gbé àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ sókè àti ère òrìṣà lórí gbogbo igi túútúú Ní gbogbo ibi gíga, wọ́n ṣun tùràrí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú wọn Wọ́n ṣe ohun búrubú tí ó rú ìbínú Olúwa sókè Wọ́n sìn òrìsà, èyí tí Olúwa ti sọ pé, Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí Olúwa kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì àti Júdà nípa gbogbo àwọn wòlíì wọn àti aríran Ẹ yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú yín Kí ẹ ṣe òfin mi àti ìlànà mi, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin tí Èmi palaṣẹ fún àwọn baba yín láti tẹ̀lé àti èyí tí mo rán síi yín nípa ìránṣẹ́ àwọn wòlíì mi Ṣùgbọ́n wọn kò ní gbọ́, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́rùn lile gẹ́gẹ́ bí i ti baba wọn, ẹni tí kò gbà Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́ Wọ́n kọ̀ ìlànà rẹ̀ àti májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú baba wọn àti ìkìlọ̀ tí ó ti fi fún wọn Wọ́n tẹ̀lé òrìṣà aláìníláárí, àwọn fún rara wọn sì jẹ́ aláìníláárí Wọ́n tẹ̀lé orílẹ̀ èdè tí ó yí wọn ká bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti kìlọ̀ fún wọn pé, Má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí wọn tí ń ṣe, wọ́n sì ṣe ohun tí Olúwa ti kà léèwọ̀ fún wọn láti ṣe Wọ́n kọ̀ gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀ wọ́n sì ṣe òrìṣà méjì fún ara wọn, wọ́n sì gbée sí ọkàn ẹ̀gbọ̀rọ̀ màlúù, àti ère òrìṣà sí ọkàn Wọ́n sì tẹrí wọn ba sí gbogbo ogun ọ̀run, wọ́n sì sin Báálì Wọ́n sì fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn rúbọ nínú iná Wọ́n sì n fọ̀ àfọ̀sẹ, wọ́n sì ń ṣe àlùpàyídà wọ́n sì ta ara wọn láti ṣe ohun búburú níwájú Olúwa , wọ́n sì mú-un bínú Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì bínú gídígídí pẹ̀lú Ísírẹ́lì ó sì mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ Èyà Júdà nìkan ṣoṣo ni ó kù, Àti pẹ̀lú, Júdà kò pa òfin Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́ Wọ́n tẹ̀lé ìhùwàsí àwọn Ísírẹ́lì tí wọ́n ṣe Nítorí náà Olúwa kọ gbogbo àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ó sì jẹ wọ́n níyà Ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn olè tí tí tí ó fi ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀ Nígbà tí ó ta Ísírẹ́lì kúrò láti ìdílé Dáfídì, wọ́n sì mú Jéróbámù ọmọ Nébátì jẹ ọba wọn Jéróbóámù sì mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yípadà kúrò ní tí tẹ̀lé Olúwa , ó sí mú kí wọn dẹ́sẹ̀ ńlá Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì forítìí nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbámù kò sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ wọn Títí tí Olúwa fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ wòlíì Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ wọn lọ sí Iṣánṣà ni Ásíríà Ọba Ásíríà mú àwọn ènìyàn láti Bábílónì, Kútà, Áfà, Hámátì àti Ṣéfáfáímù wọ́n sì dúró ní ìlú Ṣamáríà láti rọ́pò àwọn ará Ísírẹ́lì Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà Nígbà tí wọ́n gbé bẹ́ ẹ ní àkọ́kọ́, wọn kò sì bẹ̀rù Olúwa , Bẹ́ẹ̀ ni ó rán kìnnìún sí àárin wọn Wọ́n sì pa nínú wọn Wọ́n sì sọ fún ọba Ásíríà pé Àwọn ènìyàn tí ìwọ lé kúrò tí o sì fi sínú ìlú Ṣamáríà kò mọ ohun tí Olúwa ìlú náà béèrè Ó sì ti rán kìnnìún sí àárin wọn, tí ó sì ń pa wọ́n run, nítorí ènìyàn wọn kò mọ ohun tí ó béèrè Nígbà náà ọba Ásíríà pàṣẹ yìí wí pé, Mú ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó mú láti Ṣamáríà lọ padà gbé níbẹ̀ kí ó sì kọ́ àwọn ènìyàn ní, ohun tí Olúwa ilẹ̀ náà béèrè Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó ti kúrò ní Samáríà wá gbé ní Bétélì ó sì kọ́ wọn bí a ti ń sin Olúwa Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù orílẹ̀ èdè ṣe òrìṣà tirẹ̀ ní gbogbo ìlú níbi tí wọ́n gbé wà, wọ́n sì gbé wọn nínú ilé òrìṣà àti àwọn ènìyàn Ṣamáríà ó sì ṣe wọ́n sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin láti Bábílónì ṣe àgọ́ àwọn wúndíá, àwọn ọkùnrin láti Kútì ṣe Négálì, àti àwọn ènìyàn láti Hámátì ṣe Áṣímà Àti àwọn ará Áfà ṣe Nébíhásì àti Tárítakì, àti àwọn ará Ṣéfárífáímù ṣun àwọn ọmọ wọn níná gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí Adiramélékì àti Anamélékì, àwọn òrìṣà Ṣéfárfáímù Wọ́n sin Olúwa , ṣùgbọ́n wọ́n sì tún yan gbogbo ẹgbẹ́ tí ènìyàn wọn láti ṣe iṣẹ́ oyè fún wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ní ibi gíga Wọ́n sin Olúwa ṣùgbọ́n wọ́n sin òrìṣà wọn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àṣà orílẹ̀ èdè wọn láti ibi tí wọ́n ti gbé wọn wá Láti ìgbà náà wá àwọn àlùfáà wọn ṣe bí ti àtẹ̀yìnwá Wọn kò sin Olúwa tàbí kí wọ́n fi ara mọ́ ìlànà àti àṣẹ àti òfin tí Olúwa fi fún ìránṣẹ́ Jákọ́bù, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ísírẹ́lì Nígbà tí Olúwa ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó pàṣẹ fún wọn pé Ẹ má ṣe sin òrìṣà mìíràn tàbí tẹríba fún wọn, sìn wọ́n tàbí kí ẹ rúbọ sí wọn Ṣùgbọ́n Olúwa , ẹni tí ó mú yín gòkè jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú agbára ńlá àti nínà apá, òun ni ẹni náà tí ó yẹ kí ẹ sìn Òun ni ẹni tí ó yẹ kí ẹ tẹríba fún àti sí òun ni kí ẹ rúbọ fún Ó yẹ kí ẹ̀yin kí ó máa kíyèsí ara yín gidigdidi láti pa ìlànà àti àsẹ, àti òfin tí ó kọ fún un yín mọ́ Ẹ má ṣe sin ọlọ́run mìíràn Ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú tí mo ti ṣe pẹ̀lú yín mọ́ àti kí ẹ má sin ọlọ́run mìíràn Kúkú ṣin Olúwa Ọlọ́run rẹ Òun ni ẹni náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta a yín Wọn kò ní gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ wọ́n ti àtijọ́ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn wọn sin Olúwa , wọ́n sì ń sin òrìṣà wọn Títí di ọjọ́ òní ọmọ wọn àti àwọn ọmọ-ọmọ wọn sì ń ṣe bí àwọn baba wọn ti ń ṣe Heṣekíàyà Ọba Júdà Ní ọdún kẹta Hóséà ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì, Heṣekíàyà ọmọ Áhásì ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ ìjọba Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó ti di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ A bì ọmọbìnrin Ṣakaríàyà Ó sì ṣe ohun tí ó dára níwájú Olúwa , gẹ́gẹ́ bí i baba rẹ̀ Dáfídì ti ṣe Ó mú ibi gíga náà kúrò, ó sì fọ́ òkúta àwọn ère ó sì gé àwọn ère lulẹ̀ ó sì fọ́ ejò idẹ náà túútúú tí Móṣè ti ṣe, títí di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sun tùràrí sí Heṣekáyà sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì Kò sì sí ẹnìkan tí ó dàbí tirẹ̀ lára gbogbo àwọn ọba Júdà, bóyá kí ó tó jẹ tàbí lẹ́yìn rẹ̀ Ó sún mọ́ Olúwa , kò sì dẹ́kun láti tì í lẹ́yìn ó sì pa òfin Olúwa mọ́ tí ó ti fi fún Mósè Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀ ó sì ń ṣe rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé Ó ṣe ọ̀tẹ̀ sí ọba Ásíríà kò sì sìn-ín Láti ilé-ìṣọ́ títí dé ìlú olódi, ó sì pa àwọn ará Fílístínì run, àti títí dé Gásà àti agbègbè rẹ̀ Ní ọdún kẹrin ọba Heṣekáyà, nígbà tí ó jẹ́ ọdún keje Hóséà ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì Ṣálímánésérì ọba Áṣíríà yàn lára Ṣamáríà ó sì tẹ̀dó tì í Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta Ásíríà gbé e Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó Ṣamáríà ní ọdún kẹfà Heṣekáyà tí ó sì jẹ́ ọdún kẹsàn-án Hóṣéà ọba Ísírẹ́lì Ọba Áṣíríà lé Ísírẹ́lì kúrò ní Áṣíríà, wọ́n sì ṣe àtìpó wọn ní Hálà, ní Gósánì létí odò Hábórì àti ní ìlú àwọn ará Médíà Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wọn kò pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́ Ṣùgbọ́n wọ́n ti dà májẹ̀mú rẹ̀ gbogbo èyí tí Móṣè ìránṣẹ́ Olúwa ti pa láṣẹ Wọn kò fi etí wọn sílẹ̀ sí òfin wọn kò sì gbé wọn jáde Ní ọdún kẹrìnlá tí Heṣekáyà jọba, Ṣenakérúbù ọba Ásíríà kọlu gbogbo ìlú olódi ti Júdà ó sì pa wọ́n run Bẹ́ẹ̀ ni Heṣekáyà ọba Júdà rán oníṣẹ́ yìí sí ọba Áṣíríà ní Lákísì, Mo ti mú ìṣe ohun tí kò dára kúrò lọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì san ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ mi Ọba bu ọ̀ọ́dúnrún talẹ́ntì fàdákà àti ọgbọ̀n talẹ́ntì wúrà Heṣekáyà fún un ní gbogbo fàdákà tí wọ́n rí nínú ilé Olúwa àti nínú ilé ìṣúra ọba Ní àkókò yìí Heṣekáyà ọba Júdà ké wúrà tí ó wà ní ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Olúwa , kúrò àti ti òpó tí Heṣekáyà ọba Júdà ti gbéró ó sì fi fún ọba Ásíríà Ọba Ásíríà rán alákòóṣo gíga jùlọ, ìjòyè pàtàkì àti àwọn adarí pápá pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí ó pọ̀, láti Lákísì sí ọba Heṣekáyà ní Jérúsálẹ́mù Wọ́n wá sí òkè Jérúsálẹ́mù wọ́n sì dúró ní etí ìdarí omi àbàtà òkè, ní ojú ọ̀nà tó lọ sí òpópó pápá Alágbàfọ̀ Wọ́n sì pe ọba àti Eliákímù ọmọ Hílíkíyà ẹni tí í ṣe ilé olùtọ́jú, Ṣébínà akọ̀wé, àti Jóà ọmọkùnrin Ásáfù tí ó jẹ́ akọ̀wé ìrántí jáde pẹ̀lú wọn Olùdarí pápá wí fún wọn pé, Sọ fún Heṣekáyà pé  Èyí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà sọ Lórí kí ni ìwọ ń dá ìgbóyà rẹ̀ yìí Ìwọ wí pé ìwọ ni ẹ̀tà àti ti ogun alágbára ṣùgbọ́n ìwọ sọ̀rọ̀ òfìfo nìkan, lórí ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé tí ìwọ fi ń ṣe ọ̀tẹ̀ sí mi Wò ó Nísinsìn yìí ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Éjíbítì, ẹ̀rún igi pẹlẹbẹ ọ̀pá ìyè lórí ọ̀pá, èyí tí yóò wọ inú ọwọ́ ọkùnrin tí ó sì pa á lára tí ó bá fi ara tìí Irú rẹ̀ ni Fáráò ọba Éjíbítì fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e Tí ìwọ bá sì sọ fún mi pé, Àwa gbẹ́kẹ̀ wa lé Olúwa Ọlọ́run Òun ha kọ́ ní ẹnìkan náà tí ibi gíga àti àwọn pẹpẹ tí Heṣekáyà mú kúrò, tí ó wí fún Júdà àti Jérúsálẹ́mù pé, O gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí ní Jérúsálẹ́mù  Wá Nísinsìn yìí, ṣe àdéhùn pẹ̀lú ọ̀gá mi, ọba Áṣíríà Èmi yóò sì fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin tí ìwọ bá lè kó àwọn tí yóò gùn ún sí orí rẹ! Báwo ni ìwọ yóò ṣe le padà sẹ́yìn ọ̀kan lára àwọn oníṣẹ́, tí ó gbẹ̀yìn lára àwọn oníṣẹ́ ọ̀gá mi, tí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀ yín lé Éjíbítì fún àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Síwájú síi, èmi ti wá láti mú àti láti parun ibíyìí láìsí ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Olúwa fún rara rẹ̀ sọ fún mi pé kí n yára láti yan lórí ìlú yìí, kí n sì paárun   Nígbà náà Éláékímù ọmọ Hílíkíáyà, àti ṣébínà àti Jóà sọ fún olùdarí pápá pé, Jọ̀wọ́ sọ̀rọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní èdè Ṣíríà, nítorí ti ó tí yé wa, má ṣe sọ̀rọ̀ fún wa pẹ̀lú èdè Hébérù ní etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí odi Ṣùgbọ́n aláṣẹ dáhùn pé, Ṣé fún ọ̀gá rẹ àti ìwọ nìkan ní ọ̀ga mi rán mi sí láti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í sìí ṣe fún àwọn ọkùnrin tí ó jókòó lórí odo-ta ni gẹ́gẹ́ bí ìwọ, ni yóò ní láti jẹ ìgbẹ́ ará wọn kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ará wọn Nígbà náà aláṣẹ dìdé ó sì pè jáde ní èdè Hébérù pé, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásìría! Èyí ni ohun tí ọba sọ má ṣe jẹ́ kí Héṣékíáyà tàn ọ́ jẹ kò le gbà ọ́ kúrò ní ọwọ́ mi Má se jẹ́ kí Héṣékíáyà tì ọ́ láti gbàgbọ́ nínú Olúwa nípa sísọ pé, Olúwa yóò gbà wá nítòótọ́ ìlú yìí ni wọn kò ní fi lé ọba ìlú Ásíríà lọ́wọ́ Má ṣe tẹ́tí sí Héṣékíáyà Èyí ni ohun tí ọba Ásíríà sọ Ṣe àlàáfíà pẹ̀lú mi kí o sì jáde wá sí ọ̀dọ̀ sí mi Nígbà náà olúkúlùkù yín yóò jẹun láti inú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́, yóò sì mumi láti inú àmù rẹ̀, Títí tí èmi yóò fi wá mú ọ lọ sí ilé gẹ́gẹ́ bí i tìrẹ, ilẹ̀ ọkà àti ọtí wáìnì, ilẹ̀ ouńjẹ àti ọgbà àjàrà, ilẹ̀ òróró ólífì àti ti ilẹ̀ oyin yàn ìye má sì ṣe yàn ikú! Kí ẹ má ṣe gbọ́ tí Heṣekáyà, nítorí ó ń tàn yín tí ó ba tí wí pé, Olúwa yóò gbà wá Ṣé òrìṣà àwọn orílẹ̀ èdè kankan ti gba ilé rẹ lọ́wọ́ àwọn ọba Ásíríà Níbo ni àwọn òrìṣà Hámátì àti Árípádì gbé wà Níbo ni àwọn òrìṣà Ṣérárifáímù, Hẹ́nà àti ífà gbé wà Wọ́n ha gba Ṣámáríà kúrò lọ́wọ́ mi bí Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà ilẹ̀ yìí tí ó ti gbìyànjú láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi Báwo ni Olúwa yóò ṣe gba Jérúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ènìyàn náà dákẹ́ síbẹ̀ wọn kò sì sọ ohunkóhun, láti fi fèsì, nítorí ọba ti paláṣẹ, Ẹ má ṣe dáa lóhùn Nígbà náà Élíákímù ọmọ Hílíkíyà olùtọ́jú ààfin, Séríbù akọ̀wé àti Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ránsẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Héṣékíáyà, pẹ̀lú aṣọ wọn yíya, ó sì wí fún un ohun tí olùdárí pápá ti sọ Àṣọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìgbàlà Jérúsálẹ́mù Nígbà tí ọba Ẹṣkáyà gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ó sì lọ sí àgọ́ Olúwa Ó sì rán Eliákímù olùtọ́jú ààfin, Ṣébínà akọ̀wé àti olórí àlùfáà gbogbo wọn sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, sí ọ̀dọ̀ wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì Wọ́n sì sọ fún ún pé, Èyí ni ohun tí Héṣékáyà sọ ọjọ́ òní yí jẹ́ ọjọ́ ìpọ́njú àti ìbáwí àti ẹ̀gàn, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ọmọdé wá sí ojú ìbímọ tí kò sì sí agbára láti fi bí wọn Ó lè jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yóò gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ olùdarí pápá, ẹni tí ọ̀gá rẹ̀, ọba Ásíríà, ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè sẹ̀sín, yóò sì báa wí fún ọ̀rọ̀ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́ Nítorí náà gbàdúrà fún ìyókù àwọn tí ó wà láàyè Nígbà tí ìránṣẹ́ ọba Héṣékáyà lọ sí ọ̀dọ̀ Àìṣáyà, Àìṣáyà wí fún wọn pé, Sọ fún ọ̀gá rẹ, Èyí ni ohun tí Olúwa sọ pé Ẹ má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́—àwọn ọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ pẹ̀lú èyí ti ọba Áṣíríà ti sọ̀rọ̀ òdì sí mi Gbọ́! Èmi yóò rán ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ nígbà tí ó bá sì gbọ́ ariwo, yóò sì padà sí ìlú rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi yóò sì gbé gée lulẹ̀ pẹ̀lú idà   Nígbà tí olùdarí pápá gbọ́ wí pé ọba Áṣíríà ti kúrò lákìsì ó sì padà ó sì rí ọba níbi ti ó gbé ń bá Líbíńà jà Nísinsìn yìí Ṣenakéríbù sì gbọ́ ìròyìn wí pé Tíránákà, ọba Etiópíà ti Éjíbítì wá ó sì ń yan jáde lọ láti lọ bá a jagun Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tún rán onísẹ́ sí Héṣékíáyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí pé Sọ fún Héṣékíáyà ọba Júdà pé Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí o gbékalẹ̀ kí ó tàn ó jẹ nígbà tí ó wí pé, Jérúsálẹ́mù a kò ní fi lé ọwọ́ ọba Ásíríà Lọ́ọ̀tọ́ ìwọ ti gbọ́ gbogbo ohun tí ọba Ásíríà tí ó ṣe sí gbogbo àwọn ìlú, ó pa wọ́n run pátapáta Ìwọ yóò sì gbàlà Ṣé àwọn òrìṣà orílẹ̀ èdè tí a ti parun láti ọ̀dọ̀ àwọn babańlá mi gbà wọ́n là òrìṣà Gósánì, Háránì Réṣéfù àti gbogbo ènìyàn Édẹ́nì tí wọ́n wà ní Télásárì Níbo ni ọba Hámátì wa, ọba Árípádì, ọba ìlú Séfárífáímù, ti Hénà, tàbí ti Ífà gbé wà Heṣekíàyà gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì kà á Nígbà náà ó sì lọ sí òkè ilé tí a kọ́ fún Olúwa ó sì tẹ́ ẹ ṣíwájú Olúwa Heṣekáyà gbàdúrà sí Olúwa Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ń gbé ní àárin àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí gbogbo ìjọba tí ó wà láyé, ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé Dẹtí sílẹ̀, Olúwa kí o sì gbọ́ la ojú ù rẹ, Olúwa , kí o sì rí i, gbọ́ ọ̀rọ̀ Ṣenakérúbù tí ó rán láti fi bú Ọlọ́run alààyè Òtítọ́ ni, Olúwa , wí pé ọba Ásíríà ti pa orílẹ̀ èdè wọ̀nyìí run àti ilẹ̀ wọn Wọ́n ti ju òrìṣà wọn sínú iná wọn sì ti bà wọ́n jẹ́, nítorí pé wọn kì í ṣe Olúwa Ṣùgbọ́n, wọ́n jẹ́ igi àti òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ènìyàn Nísinsìn yìí Olúwa Ọlọ́run wa, gbà wá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ìjọba lórí ilẹ̀ ayé le mọ̀ pé ìwọ nìkanṣoṣo ni, Olúwa Ọlọ́run wa Nígbà náà Àìṣáyà ọmọ Ámósì rán oníṣẹ́ sí Heṣekíàyà pé Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ nípa ti Ṣenakérúbù ọba Ásíríà Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀  Wúndíá ọmọbìnrin Ṣíónì kẹ́gàn rẹ ó sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù mi orí sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti sálọ Ta ni ìwọ ti bú tí o sì kẹ́gàn rẹ̀ Lórí ta ni ìwọ ti gbé gbé ohùn rẹ sókè tí ó sì gbé ojú sókè sí ọ ní ìgbéraga Lórí ẹni mímọ́ ti Ísírẹ́lì! Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ Ìwọ ti ṣe ìkójọpọ̀ èébú sí Olúwa Ìwọ sì ti sọ pé, Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi Èmi sì ti fi dé orí àwọn òkè ńlá, ibi gíga jùlọ ní Lébánónì Mo sì ti gé igi gíga jùlọ kédárì lulẹ̀, àti àyò igi fírì rẹ̀ Mo ti dé ibi orí òkè ìbùwọ́ ẹ̀gbẹ́ kan ibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ Mo ti gbẹ́ kàǹga ní ilẹ̀ àjèjì Mo sì mu omi níbẹ̀ Pẹ̀lú àtẹ́lẹṣẹ̀ mi, Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi odò tí ó wà ní Éjíbítì  Ṣé ìwọ kò tí ì gbọ́ Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn mo yàn án Ní ọjọ́ ogbó ni mo ṣètò rẹ̀ nísinsìn yìí mo ti mú wá sí ìkọjá pé ìwọ ti yí ìlú olódi padà dí òkítì àlàpà òkúta Àwọn ènìyàn wọn ń gbẹ nípa, wọ́n ti dàá láàmú wọ́n sì ti sọọ́ di ìtìjú Wọ́n dà bí koríko ìgbẹ́ lórí pápá, gẹ́gẹ́ bí ọkà tí ó rẹ̀ dànù kí ó tó dàgbà sókè, gẹ́gẹ́ bí fífún ọkà tí ó hù jáde  Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọ dúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbí lọ àti bí ìwọ ṣe ikáanú rẹ sí mi Ṣùgbọ́n ikáanú rẹ sí mi àti ìrora rẹ dé etí mi, Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imú rẹ àti ìjánú mi sí ẹnu rẹ, èmi yóò mú ọ padà nípa wíwá rẹ Èyí yóò jẹ́ àmìn fún ọ, ìwọ Heṣekíàyà Ọdún yìí ìwọ yóò jẹ ohun tí ó bá hù fún rara rẹ̀, àti ní ọdún kejì ohun tí ó bá hù jáde láti inú iyẹn Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, gbìn kí o sì kórè, gbin ọgbà àjàrà kí o sì jẹ èṣo rẹ̀ Lẹ́ẹ̀kan sí i ìyókù ti ilé Júdà yóò sì tún hu gbòǹgbò lábẹ́, yóò sì so èṣo lókè Láti inú Jérúsálẹ́mù ní àwọn ìyókù yóò ti wá àti láti orí òkè Ṣíónì ni ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ṣá àsálà Ìtara Olúwa àwọn ọmọ ogun yóò ṣe èyí Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa ṣọ nípa ti ọba Áṣíríà Kò ní wọ ìlú yìí tàbí ta ọfà síbí Kò ní wá níwájú rẹ pẹ̀lú àpáta tàbí kó ìdọ̀tí àgbò sí ọ̀kánkán rẹ Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóò padà kì yóò wọ ìlú ńlá yìí, ni Olúwa wí Èmi yóò dá ààbò bo ìlú ńlá yìí, èmi yóò sì paámọ́ fún èmi tìkálára mi àti fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi Ní alẹ́ ọjọ́ náà, ańgẹ́lì Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní ibùdó àwọn ará Aṣíríà Nígbà tí wọ́n sì dìde dúró ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì níbẹ̀ ni gbogbo òkú wà! Bẹ́ẹ̀ ni Ṣenakérúbù ọba Áṣíríà wọ àgọ́ ó sì padà, ó sì padà sí Nínéfè ó sì dúró níbẹ̀ Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn nínú ilé òrìṣà Nísírókù, ọmọkùnrin rẹ̀ Adiramélékì àti Ṣárésérì gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Árárátì Ésáráhádónì ọmọkùnrin rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀ Èlíjà Gun Kẹ̀kẹ́ Iná Lọ Sí Ọ̀run Nígbà tí Ọlọ́run ń fẹ́ gbé Èlíjà lọ sí òkè ọ̀run nínú àjà, Èlíjà àti Èlíṣà wà ní ọ̀nà láti Gílgálì Èlíjà wí fún Èlíṣà pé, Dúró níbí Olúwa rán mi lọ sí Bétélì Ṣùgbọ́n Èlíṣà wí pé, Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa wà láyé àti gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Bétélì Àwọn ọmọ wòlíì ní Bétélì jáde wá sí ọ̀dọ̀ Èlíṣà wọ́n sì béèrè pé, Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olúwa yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀, Èlíṣà dáhùn Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ Nígbà náà Èlíjà sì wí fún un pé, Dúró níbí, Èlíṣà Olúwa ti rán mi lọ sí Jẹ́ríkò Ó sì dá a lóhùn pé, Bí ó ti dájú pé Olúwa yè àti tí ìwọ náà yè, Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀ Wọ́n sì jọ lọ sí Jẹ́ríkò Àwọn ọmọ wòlíì tí ó wà ní Jẹ́ríkò sì gòkè tọ Èlíṣà wá wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Ṣé ìwọ mọ̀ wí pé Olúwa yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀, Ó dá wọn lóhùn, Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀ Nígbà náà Èlíjà wí fún un pé, Dúró níbí Olúwa rán mi lọ sí Jọ́dánì Ó sì dá a lóhùn pé, Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ wí pé, Olúwa yè àti gẹ́gẹ́ bí o ti yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì sì jọ ń lọ Àádọ́ta àwọn ọkùnrin ọmọ wòlíì sì lọ láti lọ dúró ní ọ̀nà jínjìn, wọ́n sì kọ ojú da ibi tí Èlíjà àti Èlíṣà ti dúró ní Jọ́dánì Èlíjà sì mú agbádá ó sì ká a sókè ó sì lu omi náà pẹ̀lú rẹ̀ Omi náà sì pín sí ọ̀tún àti sí òsì, àwọn méjèèjì sì rékọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ̀ Nígbà tí wọ́n rékọjá, Èlíjà sì wí fún Èlíṣà pé, Sọ fún mi, kí ni èmi lè ṣe fún ọ kí ó tó di wí pé wọ́n gbà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ Jẹ́ kí èmi kí ó jogún ìlọ́po méjì ẹ̀mí rẹ Ó dá a lóhùn Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro, Èlíjà wí pé, Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń rìn lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pọ̀, lọ́gán kẹ̀kẹ́ iná àti ẹsin iná yọ sí wọn ó sì ya àwọn méjèèjì nípa, Èlíjà sì gòkè lọ sí ọ̀run pẹ̀lú àjà Èlíṣà rí èyí ó sì kígbe sókè, Baba mi! Baba mi! Kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Ísírẹ́lì! Èlíṣà kò sì rí i mọ́ Ó sì mú aṣọ ara rẹ̀ ó sì fà wọ́n ya sọ́tọ̀ Ó sì mú agbádá tí ó ti jábọ́ láti ọ̀dọ̀ Èlíjà ó sì padà lọ, ó sì dúró lórí bèbè Jọ́dánì Ó sì mú agbádá náà tí ó jábọ́ láti ọwọ́ rẹ̀, ó sì lu omi pẹ̀lú rẹ̀ Níbo ni Olúwa Ọlọ́run Èlíjà wà Ó bèèrè Nígbà tí ó lu omi náà, ó sì pín sí apá ọ̀tún àti sí òsì, ó sì rékọjá Àwọn ọmọ wòlíì láti Jẹ́ríkò, tí wọ́n ń wò, wí pé, Ẹ̀mí Èlíjà simi lé Èlíṣà Wọ́n sì lọ láti lọ bá a, wọ́n sì dojú bolẹ̀ níwájú rẹ̀ Wò ó, wọ́n wí pé, Àwa ìránṣẹ́ ni àádọ́ta ọkùnrin alágbára Jẹ́ kí wọ́n lọ láti lọ wá ọ̀gá rẹ wá Bóyá ẹ̀mí Olúwa ti gbé e sókè, ó sì gbé e kalẹ̀ lórí òkè ńlá tàbí lórí ilẹ̀ Rárá, Èlíṣà dá a lóhùn pé, Má ṣe rán wọn Ṣùgbọ́n wọ́n forítì í títí ojú fi tì í láti gbà Ó wí pé, Rán wọn Wọ́n sì rán àádọ́ta ènìyàn tí ó wá a fún ọjọ́ mẹ́ta ṣùgbọ́n wọn kò ríi Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Èlíṣà, tí ó dúró ní Jẹ́ríkò, ó wí fún wọn pé, Ṣé èmi kò sọ fún un yín kí ẹ má lọ Àwọn ọkùnrin ìlú wí fún Èlíṣà, pé Wò ó, Olúwa wa, ìtẹ̀dó ìlú yìí dára, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i, ṣùgbọ́n omi náà kò dára ilẹ̀ náà sì jẹ́ aṣálẹ̀ Ó sì wí pé, Mú àwokòtò tuntun fún mi wá, kí o sì mú iyọ̀ sí inú rẹ̀ Wọ́n sì gbé e wá fún un Nígbà náà ó sì jáde lọ sí ibi orísun omi, ó sì da iyọ̀ sí inú rẹ̀, ó wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí Èmi ti wo omi yìí sàn Kò ní mú ikú wá mọ́ tàbí mú ilẹ̀ náà ṣá   Omi náà sì ti dára ni mímu títí di òní, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Èlíṣà ti sọ Láti ibẹ̀ Èlíṣà lọ sókè ní Bétélì gẹ́gẹ́ bí ó ti ń rìn lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọ̀dọ́ kan jáde wá láti ìlú náà wọ́n sì fi ṣe ẹlẹ́yà Má a lọ sókè ìwọ apárí! Wọ́n wí pé Má a lọ sókè ìwọ apárí! Ó sì yípadà, ó sì wò wọ́n ó sì fi wọ́n bú ní orúkọ Olúwa Nígbà náà béárì méjì sì jáde wá láti inú igbó ó sì lu méjìlélógójì lára àwọn ọ̀dọ́ náà Ó sì lọ sí orí òkè Kámẹ́lì láti ibẹ̀ ó sì padà sí Samáríà Àìsàn Heṣekáyà Ní ayé ìgbà wọ̀n-ọn-nì Heṣekáyà ṣe àìsàn ó sì wà ní ojú ikú Wòlíì Àìsáyà ọmọ Ámósì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa sọ tún ilé rẹ ṣe, ṣùgbọ́n ìwọ yóò kú o kò níí gbádùn Heṣekáyà yí ojú rẹ̀ padà sí ògiri ó sì gbàdúrà sí Olúwa pé, Rántí, Olúwa mi, bí èmi ṣe rìn níwájú rẹ àti pẹ̀lú bí èmi ṣe jẹ́ olóòtọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn ìfọkànsìn mi tí èmi sì ti ṣe ohun tí ó dára níwájú rẹ Heṣekáyà sunkún kíkorò Kí ó tó di wí pé Àìṣáyà jáde kúrò ní àárin àgbàlá ààfin, ọ̀rọ̀ Olúwa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé Lọ padà kí o sì sọ fún Heṣekáyà, olórí àwọn ènìyàn mi pé, Èyí ni ohun tí Olúwa , Ọlọ́run baba rẹ Dáfídì sọ Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ Èmi yóò wò ó sàn Ní ọjọ́ kẹta láti ìsinsìnyìí, ìwọ yóò lọ sókè ilé tí a kọ́ fún Olúwa Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀dógún kún ọjọ́ ayé rẹ Èmi yóò sì gbà ọ́ àti ìlú ńlá yìí láti ọwọ́ ọba Ásíríà Èmi yóò sì dábòbò ìlú yìí nítorí ti èmi tìkára mi àti nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi   Nígbà náà ni Àìṣáyà wí pé, Mú ọ̀pọ̀tọ́ tí a sù bí i gàrí Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì fi sí owo náà, ara rẹ̀ sì yá Heṣekáyà sì béèrè lọ́wọ́ Àìṣáyà pé, Kí ni yóò jẹ́ àmìn pé Olúwa yóò wò mí sàn àti wí pé èmi yóò lọ sókè sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa láti ọjọ́ kẹta títí di òní Àìṣáyà dáhùn pé, Èyí ni àmìn tí Olúwa fún ọ wí pé Olúwa yóò ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí kí òjìji lọ ṣíwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, tàbí kí ó padà lọ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá Ó jẹ́ ohun ìrọ̀rùn fún òjìji láti lọ ṣíwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, Heṣekáyà wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí ó lọ padà ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá Nígbà náà wòlíì Àìṣáyà ké pe Olúwa , Olúwa sì ṣe òjìji padà sí ìgbésẹ̀ mẹ́wàá ó ti sọ̀kalẹ̀ ní òpópó ọ̀nà Áhásì Ní àkókò náà ni Méródákì-Báládánì ọmọ Báládánì ọba Bábílónì rán ṣẹ́ ìwé àti ẹ̀bùn sí Heṣekáyà nítorí tí ó ti gbọ́ nípa àìsàn Heṣekáyà Heṣekáyà gba ìránṣẹ́ náà ó sì fi hàn wọ́n, gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé ìṣúra—sílífà, àti wúrà, àti tùràrí, àti òróró dáradára àti Ìhámọ́ra àti gbogbo èyí tí a rí lára ìṣúra rẹ̀ Kò sí nǹkan nínú ààfin rẹ̀ tàbí nínú gbogbo ìjọba rẹ̀ tí Heṣekáyà kò sì fi hàn wọ́n Nígbà náà Àìṣáyà wòlíì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Heṣekáyà ó sì béèrè pé, Kí ni àwọn ọkùnrin náà sọ, àti níbo ni wọ́n ti ń bọ̀ wá Lati ìlú jínjìn réré, Hesekíáyà dáhùn Wọ́n wá láti Bábílónì Wòlíì náà béèrè pé, Kí ni wọ́n rí ní ààfin rẹ Wọ́n rí gbogbo nǹkan ní ààfin mi, Heṣekáyà wí pé Kò sí nǹkankan lára àwọn ìṣúra tí èmi kò fi hàn wọ́n Nígbà náà Àìsáyà wí fún Heṣekáyà pé, Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Àkókò náà yóò sì dé nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà ní ààfin àti gbogbo ohun tí baba rẹ̀ ti kó pamọ́ sókè títí di ọjọ́ Òní, wọn yí ó gbe lọ sí Bábílónì, kò sí ohun tí yóò kù, ni Olúwa wí Àti díẹ̀ nínú àwọn ilé rẹ, ẹran ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀, tí wọn yóò bí fún ọ, ni wọn yóò kó lọ, wọn yóò sì di ìwọ̀fà ní ààfin ọba Bábílónì Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ ó dára Heṣekáyà dáhùn Nítorí ó rò wí pé, Kò ha dára àlàáfíà àti òtítọ́ ní ọjọ́ ayé mi Ní ti àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tó kù nípa ìjọba Heṣekáyà, gbogbo ohun tí ó ṣe tan àti bí ó ti ṣe adágún omi àti ọ̀nà omi náà nípa èyí tí ó gbé wá omi sínú ìlú ńlá, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìgbéṣẹ̀ ayé àwọn ọba àwọn Júdà Heṣekáyà sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ Mánásè ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Mánásè Ọba Júdà Mánásè jẹ́ ẹni ọdún méjìlá nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ìjọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Héfisíbà Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa , ó sì tẹ̀lé iṣẹ́ ìríra tí àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekíáyà tí ó parun kọ́ Ó sì tún gbé pẹpẹ dìde fún Báálì ó sì ṣe ère-òrìṣà, gẹ́gẹ́ bí Áhábù ọba Ísírẹ́lì ti ṣe Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n Ó sì kọ́ pẹpẹ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa , èyí tí Olúwa ti sọ pé, Ní Jérúsálẹ́mù ni èmi yóò kọ orúkọ mi sí Ní àgbàlá méjèèjì ilé Olúwa , ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú Olúwa , ó sì mú un bínú Ó fi ọmọ ara rẹ̀ rúbọ̀ nínú iná, a máa ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ àti àlùpàyídà, ó sì máa ń bá àwọn òku àti oṣó lò Ó hùwà búburú púpọ̀ ní ojú Olúwa láti mú un bínú Ó sì gbé fínfín ère òrìṣà tí ó ti ṣe ó sì gbé e sínú ilé Olúwa , èyí tí Olúwa ti sọ fún Dáfídì àti sí ọmọ rẹ̀ Ṣólómónì, Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jérúsálẹ́mù, tí èmi ti yàn jáde lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, èmi yóò kọ orúkọ mi títí láéláé Èmi kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹ̀ kúrò láti ilẹ̀ tí èmi fi fún àwọn babańlá wọn tí ó bá jẹ́ wí pé wọn yóò ṣe àkíyèsí láti ṣe gbogbo ohun tí èmi ti paláṣẹ fún wọn kí wọn sì pa gbogbo òfin tí ìránṣẹ́ mi Móṣè fi fún wọn mọ́ Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tẹ́tí Mánásè tàn wọ́n ṣíwájú, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè ṣe búburú ju gbogbo orílẹ̀ èdè tí Olúwa tí parun níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ Olúwa sì wí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì pé Mánásè ọba Júdà ti ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ohun ìríra Ó ti ṣe ohun búburú jùlọ ju àwọn ará Ámórì lọ ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ tí ó sì ti ṣáájú Júdà sínú ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn ère rẹ̀ Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí Èmi le è lọ mú irú ibi báyìí wá sórí Jérúsálẹ́mù àti Júdà kí gbogbo etí olúkúlùkù tí ó gbọ́ nípa rẹ̀ le è hó Èmi yóò sì nà okùn ìwọ̀nkan tí a lò lórí Jérúsálẹ́mù àti lórí Ṣamáríà àti òjé ìdiwọ̀n ti a lòlò lórí ilé Áhábù Èmi yóò sì nu Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ọkàn tí ń nu àwokòtò nù ti o n nù un tí o sì ń dorí rẹ̀ kodò Èmi yóò sì kọ ìyókù àwọn ìní mi sílẹ̀ èmi yóò sì kó wọn lé àwọn ọ̀ta wọn lọ́wọ́ Wọn yóò sì di ìkógun àti ìjẹ fún gbogbo àwọn ọ̀ta wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣe búburú ní ojú mi, wọ́n sì ti mú mi bínú láti ọjọ́ tí babańlá wọn ti jáde wá láti Éjíbítì títí di òní yìí Pẹ̀lúpẹ̀lù, Mánásè pẹ̀lú ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ tí ó kún Jérúsálẹ́mù láti ìkangun dé ìkangun ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti mú Júdà ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n lè ṣe ohun búburú ní ojú Olúwa Ní ti iṣẹ́ ìyókù ti ìjọba Mánásè, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ṣé wọ́n kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Júdà Mánásè sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ọgbà ààfin rẹ̀, ọgbà Úṣà Ámónì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Ámónì jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó jọba Orúkọ bàbá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Méṣúlémétì ọmọbìnrin Hárúsì ó wá láti Jótíbà, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjì Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa àti gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Mánásè ti ṣe Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà baba rẹ̀ Ó sì ń sin àwọn ère tí baba rẹ̀ ń sìn, ó sì ń tẹrí rẹ̀ ba fún wọn Ó sì kọ Olúwa Ọlọ́run baba rẹ̀ sílẹ̀ kò sì rìn ní ọ̀nà ti Olúwa Àwọn ìránṣẹ́ Ámónì dìtẹ̀ lórí rẹ̀ wọ́n sì lu ọba pa ní àárin ilé rẹ̀ Nígbà náà àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí ó dìtẹ̀ sí ọba Ámónì, wọ́n sì fi Jòsíáyà ọmọ rẹ̀ jọba ní àyè rẹ̀ Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ti ìjọba Ámónì àti ohun tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Júdà Wọ́n sì sin ín sínú isà òkú nínú ọgbà Úṣà Jòṣíáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ A Rí Ìwé Òfin Jòsáyà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jédídà ọmọbìnrin Ádáyà ó wá láti Bósíkátì Ó sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa , ó sì rìn ní ọ̀nà Dáfídì bàbá a rẹ̀, kò sì yípadà sí apá ọ̀tún tàbí sí apá òsì Ní ọdún kejìdínlógún tí ó fi jọba Ọba Jòsáyà rán akọ̀wé, Ṣáfánì ọmọ Ásálíà, ọmọ Mésúlámù, sí ilé Olúwa Ó wí pé Gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Hílíkíyà olórí àlùfáà, kí o sì jẹ́ kí ó sírò iye owó tí a mú wá sí ilé Olúwa , tí àwọn olùṣọ́nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Ẹ sì jẹ́ kí wọn ó fi lé àwọn ọkùnrin tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé Olúwa Kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ọkùnrin san án fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ilé Olúwa ṣe Àwọn gbẹ́nà-gbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn akọ́lé Bákan náà ni wọ́n ra igi àti òkúta ọlọ́ṣọ̀ọ́ láti fi tún tẹ́ḿpìlì ṣe Ṣùgbọ́n wọn kò ní láti ṣe ìṣirò fún owó náà tí a fi fún wọn, nítorí wọ́n ṣe òtítọ́ Hílíkíyà olórí àlùfáà sọ fún Ṣáfánì akọ̀wé pé, Èmi rí ìwé òfin nílé Olúwa Ó fi fún Ṣáfánì, ẹni tí ó kà á Nígbà náà, Ṣáfánì akọ̀wé lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ó sì sọ fún un pé Àwọn ìjòyè rẹ ti san owó náà tí ó wà nínú ilé Olúwa Èmi sì ti fi lé ọwọ́ àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ náà àti àwọn alábojútó nílé Olúwa Nígbà náà Ṣáfánì akọ̀wé sọ fún ọba pé, Hílíkíyà àlùfáà ti fún un ní ìwé kan Ṣáfánì kà lára rẹ̀ níwájú ọba Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya Ó pa àsẹ yìí fún Áhíkámù àlùfáà, Hílíkíyà ọmọ Ṣáfánì, Ákíbórì ọmọ Míkáyà, àti Ṣáfánì akọ̀wé àti Aṣahíáyà ìránṣẹ́ ọba Lọ, ẹ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi àti fún àwọn ènìyàn àti fún gbogbo Júdà nípa ohun tí a kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí Gíga ni ìbínú Olúwa tí ó ń jó sí wa nítorí àwọn baba wa kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí wọn kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ níbẹ̀ nípa wa Hílíkíyà àlùfáà, Áhíkámù àti Ákíbórì pẹ̀lú Ṣáfánì, lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin Húlídà láti lọ bá a sọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ aya Ṣálúmù ọmọ Tíkífà ọmọ Háríhásì alábojútó ibi ìpa aṣọ mọ́ sí Ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù ní ìdà kejì Ó wí fún wọn pé, Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Sọ fún ọkùnrin tí ó rán an yín sími, Èyí ni ohun tí Olúwa wí Èmi yóò mú ibi wá sí ibí àti àwọn ènìyàn rẹ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé tí ọba Júdà ti kà Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì tún ṣun tùràrí fún ọlọ́run mìíràn Wọ́n sì mú mi bínú nípa gbogbo àwọn òrìṣà tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn dá Ìbínú mi yóò ru sí ibí yìí, kì yóò sì rọlẹ̀ Sọ fún ọba Júdà tí ó rán yín láti bèrè lọ́wọ́ Olúwa , Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí nípa ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí ìwọ ti gbọ́ Nítorí tí ọkàn rẹ rọ̀, tí ìwọ sì ti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa , nígbà tí ìwọ gbọ́ èyí tí mo sọ sí ibí yìí àti sí àwọn ènìyàn rẹ pé wọn yóò di ahoro àti ẹni ègún tí ìwọ sì fa aṣọ ọ̀ rẹ ya pẹ̀lú níwájú mi Èmi ti gbọ́ tìrẹ, ni Olúwa wí Nítorí náà èmi yóò kó ọ jọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baba à rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà Ojú rẹ kì yóò rí gbogbo àwọn ibi tí èmi yóò mú wá bá ibí yìí Bẹ́ẹ̀ wọ́n mú èsì rẹ̀ padà tọ ọba wá Jòṣíàyà Sọ Májẹ̀mú Dọ̀tún Nígbà náà ọba pe gbogbo àwọn àgbààgbà Júdà àti Jérúsálẹ́mù jọ Ó gòkè lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Júdà, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù, àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì—gbogbo àwọn ènìyàn láti ibi kéékèèkéé sí ńlá Ó kàá sí etí igbọ́ ọ wọn, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé májẹ̀mú, tí a ti rí nínú ilé Olúwa Ọba sì dúró lẹ́bà òpó, ó sì sọ májẹ̀mú di titun níwájú Olúwa láti tẹ̀lé Olúwa àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, ìlànà àti òfin pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo ẹ̀mí rẹ̀, àti láti ṣe ìwádìí àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn sì ṣèlérí fúnra wọn sí májẹ̀mú náà Ọba sì pàṣẹ fún Hílíkíáyà olórí àlùfáà àti àwọn, àlùfáà tí ó tẹ̀lée ní ipò àti àwọn olùsọ́nà láti yọ kúrò nínú ilé Olúwa gbogbo ohun èlò tí a ṣe fún Báálì àti Áṣérà àti gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run Ó sì sun wọ́n ní ìta Jérúsálẹ́mù ní pápá pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì Ó sì kó eérú wọn jọ sí Bétélì Ó sì kúrò pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà tí a yàn láti ọwọ́ ọba Júdà láti ṣun tùràrí ní ibi gíga ti ìlú Júdà àti àwọn tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká Àwọn tí ó ń sun tùràrí sí Báálì, sí oòrùn àti òṣùpá, sí àwọn àmì ìràwọ̀ àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run Ó mú ère òrìṣà láti ilé Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì ní ìta Jérúsálẹ́mù, ó sì ṣun wọ́n níbẹ̀ Ó lọ̀ ọ́ bí atíkè ó sì fọ́n ekuru náà sórí iṣà òkú àwọn ènìyàn tí ó wọ́pọ̀ Ó sì wó ibùgbé àwọn tí ń ṣe panṣágà lọ́kùnrin o tí ojúbọ wọn lulẹ̀ Tí ó wà nínú ilé Olúwa àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún Áṣérà Jòṣíáyà kó gbogbo àwọn àlùfáà láti àwọn ìlú Júdà ó sì ba ibi mímọ́ wọ̀n-ọn-nì jẹ́ láti Gébà sí Béríṣébà, níbi tí àwọn àlùfáà ti ṣun tùràrí Ó wó àwọn ojúbọ lulẹ̀ ní ẹnu ìlẹ̀kùn—ní ẹnu ọ̀nà à bá wọlé ti Jóṣúà, baálẹ̀ ìlú ńlá tí ó wà ní apá òsì ẹnu ìlẹ̀kùn ìlú ńlá Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, àwọn àlùfáà ibi gíga kò jọ́sìn ní ibi pẹpẹ Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, wọ́n jẹ nínú àkàrà aláìwú pẹ̀lú àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn Ó sì ba ohun mímọ́ Tófẹ́tì jẹ́, tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Beni-Hínómì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan tí ó lè lò ó fún ẹbọ rírú fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin nínú iná sí Mólékì Ó sì kúrò láti ẹnu ọ̀nà àbáwọlé sí ilé Olúwa , àwọn ẹṣin tí àwọn ọba Júdà ti yà sọ́tọ̀ sí oòrùn náà Wọ́n wà nínú ilé ẹjọ́ lẹ́bàá yàrá oníṣẹ́ tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Nátanì-Mélékì Jòṣíáyà sì ṣun àwọn kẹ̀kẹ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún oòrùn Ó wó o palẹ̀ pẹpẹ tí àwọn ọba Júdà ti wọ́n gbé dúró ní ori òrùlé lẹ́bá yàrá òkè ti Áhásì pẹ̀lú àwọn pẹpẹ tí Mánásè ti kọ́ nínú ilé ẹjọ́ méjèèjì sí ilé Olúwa Ó sí wọn kúrò níbẹ̀, ó fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ Ó sì da ekuru wọn sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì Ọba pẹ̀lú ba ohun mímọ́ àwọn ibi gíga jẹ́ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Jérúsálẹ́mù ní ìhà gúṣù ti òkè ìbàjẹ́—èyí tí Ṣólómónì ọba Ísírẹ́lì ti kọ́ fún Ásítórétì ọlọ́run ìríra àwọn ará Ṣídónì, fún Kémóṣì ọlọ́run ìríra àwọn ará Móábù àti fún Mólékì, ọlọ́run ìríra àwọn ènìyàn Ámónì Jòṣíàh fọ́ òkúta yíyà sọ́tọ̀, ó sì gé òpó Áṣérà lulẹ̀ Ó sì bo ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ ẹ rẹ̀ pẹ̀lú egungun ènìyàn Àní pẹpẹ tí ó wà ní Bétélì ibi gíga tí Jéróbóámù ọmọ Nébátí dá Tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti ṣẹ̀—Àní pẹpẹ náà àti ibi gíga tí ó fọ́ túútúú Ó jó àwọn ibi gíga, ó sì lọ̀ ọ́ sí ẹ̀tù, ó sì ṣun òpó Áṣérà pẹ̀lú Nígbà náà, Jòṣíà wò yíká, nígbà tí ó sì rí àwọn iṣà òkú tí ó wà níbẹ̀ ní ẹ̀bá òkè, ó yọ egungun kúrò lára wọn, ó sì jó wọn lórí pẹpẹ láti sọ ọ́ di èérí ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí a ti kéde láti ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ Ọba sì béèrè, pé Kí ni ọwọ́n iṣà òkú yẹn tí mo rí Àwọn ọkùnrin ìlú ńlá wí pé, Ó sàmì sí iṣà òkú ènìyàn Ọlọ́run tí ó wá láti Júdà, tí ó sì kéde ìdojúkọ pẹpẹ Bétélì, ohun kan wọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe sí wọn Fi sílẹ̀ nìkan, Ó wí pé Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó da àwọn egungun rẹ̀ láàmú Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá egungun rẹ̀ sí àti ti àwọn wòlíì tí ó wá láti Ṣamáríà Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Bétélì, Jòṣíàh sì kúrò, ó sì ba gbogbo ojúbọ òrìṣà ti ibi gíga jẹ́, tí àwọn ọba Ísírẹ́lì ti kọ́ sí àwọn ìlú ní Ṣamáríà, tí ó ti mú Olúwa bínú Jòṣíáyà dúńbú gbogbo àwọn àlùfáà ibi gíga lórí pẹpẹ Ó sì ṣun egungun ènìyàn lórí wọn Nígbà náà, ó padà lọ sí Jérúsálẹ́mù Ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé Ẹ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa Ọlọ́run yín, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sí inú ìwé májẹ̀mú yìí Kì í ṣe láti ọjọ́ àwọn Júdà tí ó tọ́ Ísírẹ́lì, ní gbogbo àwọn ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì àti àwọn ọba Júdà Ṣé wọ́n ti ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá rí Ṣùgbọ́n ní ọdún kejìdínlógún tí ọba Jòṣíà, àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí sí Olúwa ní Jérúsálẹ́mù Síwájú sí, Jòsíáyà sì lé àwọn oṣó àti àwọn ẹ̀mí ní àwọn ìdílé, àti àwọn òrìṣà àti gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí a rí ní Júdà àti ní Jérúsálẹ́mù Èyí ni ó ṣe kí ó le è mú ọ̀rọ̀ òfin náà ṣe ní ti òfin tí a kọ sínú ìwé tí Hílíkíyà àlùfáà ti rí nínú ilé Olúwa Kò sì sí ọba kankan níwájú tàbí lẹ́yìn Jóṣíáyà tí ó dàbí rẹ̀, tí ó yí padà sí olúwa tinútinú àti gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tọkàntọkàn pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí i rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin Móṣè Bí ó ti wù kí ó rí Olúwa kò yípadà kúrò nínú ìmúná ìbínú ńlá rẹ̀ tí ó jó sí Júdà, nítorí gbogbo èyí tí Mánásè ti ṣe láti mú un bínú Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí pé, Èmi yóò mú Júdà kúrò pẹ̀lú níwájú mi, bí mo ti mú Ísírẹ́lì, èmi yóò sì kó Jérúsálẹ́mù, ìlú ńlá tí mo yàn àti ilé Olúwa yìí, nípa èyí tí mo sọ, Níbẹ̀ ni orúkọ mi yóò wà   Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jòṣíà, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà Nígbà tí Jòṣíà jẹ́ ọba, Fáráò Nékò ọba Éjíbítì gòkè lọ sí odò Yúfúrátè láti lọ ran ọba Ásíríà lọ́wọ́ Ọba Jòṣíáyà jáde lọ láti lọ bá a pàdé lójú ogun ṣùgbọ́n Nékò dojúkọ ọ́, ó sì pa á ní Mégídò Ìránṣẹ́ Jòṣíáyà gbé ara rẹ̀ wá nínú kẹ̀kẹ́ láti Mègídò sí Jérúsálẹ́mù ó sì sin ín sínú iṣà òkú rẹ̀ Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jéhóáhásì ọmọ Jòṣíáyà Ó fi àmì òróró yàn án, ó sì ṣe é ní ọba ní ipò bàbá a rẹ̀ Jéhóáhásì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́talélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Hámútalì ọmọbìnrin Jeremíáyà ó wá láti Líbínánì Ó ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe Fáráò Nékó sì fi sí inú ìdè ní Ríbílà ní ilẹ̀ Hámátì, kí ó má ba à lè jọba ní Jérúsálẹ́mù Ó sì tan Júdà jẹ fun iye ìwọ̀n ẹgbẹ̀rin talẹ́ntì wúrà kan Fáráò Nékò ṣe Élíákímù ọmọ Jòṣíàh ní ọba ní ipò baba rẹ̀ Jòsáyà Ó sì yí orúkọ Élíákímù padà sí Jéhóíákímù Ṣùgbọ́n ó mú Jéhóáhásì, ó sì gbéé lọ sí Éjíbítì, níbẹ̀ ni ó sì kú Jéhóíákímù sì san fún Fáráò Nékónì fàdákà àti wúrà tí ó béèrè Lati ṣe bẹ́ẹ̀, ó bu owó òde fún ilẹ̀ náà láti san, ó fi agbára gba fàdákà àti wúrà láti ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ní ìbámu pẹ̀lú iye tí a pín Jéhóíákímù jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlá orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣébídà ọmọbìnrin Pédáíáyà ó wá láti Rúmà Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe Jéhóíákínì Ọba Júdà Nígbà ìjọba Jéhóíákímù, Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì gbógun sí ilẹ̀ náà, Jéhóíákímù sì di ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta Ṣùgbọ́n nígbà náà ó yí ọkàn rẹ̀ padà ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinéṣárì Olúwa sì rán àwọn ará Bábílónì, àwọn ará Aráméánì, àwọn ará Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì Ó rán wọn láti pa Júdà run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípaṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Júdà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa , láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Mánásè àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí Olúwa kò sì fẹ́ láti dáríjìn Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jéhóíákímù, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Júdà Jéhóíákímù sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jéhóíákínì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Ọba Éjíbítì kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Bábílónì ti gba gbogbo agbégbé rẹ̀ láti odò Éjíbítì lọ sí odò Éúférátè Jéhóíákínì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta Orúkọ ìyá a rẹ̀ a sì máa jẹ́ Néhúṣítà ọmọbìnrin Élínátanì ó wá láti Jérúsálẹ́mù Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa , gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe Ní àkókò náà àwọn ìjòyè Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì wá sílẹ̀ Jérúsálẹ́mù wọ́n sì gbé dófì kalẹ̀ fún un, Nebukadinéṣárì fúnrarẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìjòyè fi ogun dótì í Jéhóíákímù ọba Júdà àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Bábílónì ó mú Jéhóíákínì ẹlẹ́wọ̀n Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nebukadinéṣárì kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé Olúwa àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Ṣólómónì ọba Ísírẹ́lì Ti kọ́ fún Olúwa , Ó kó wọn lọ sí ìgbékùn gbogbo Jérúsálẹ́mù gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárún ún, àwọn talákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù Nebukadinéṣárì mú Jéhóíákínì ní ìgbékùn lọ sí Bábílónì Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ile náà Ọba Bábílónì àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin alágbára ọkùnrin, alágbára tí ó yẹ fún ogun, àti àwọn ẹgbẹ̀rùn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ Ó sì mú Mátanáyà arákùnrin baba Jéhóíákínì, ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ṣedekáyà Ṣedekáyà jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlá Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútalì ọmọbìnrin Jeremáyà ó sì wá láti Líbínà Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa , gẹ́gẹ́ bí Jéhóíákínì ti ṣe Nítorí tí ìbínú Olúwa , ni gbogbo èyí ṣe sẹ sí Jérúsálẹ́mù, àti Júdà, ní òpin ó ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀ Nísinsìn yìí Ṣedekíàyà sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì Wọ́n tú Jéhóíákínì sílẹ̀ Nígbà tí ó di ọdún kẹsàn án ìjọba Ṣédékíàyà Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá, Nebukadinésárì ọba Bábílónì yan lọ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀ Ó sì pàgọ́ sí ìta ìlú ó sì mu àwọn isẹ ìdọ̀tì fi yí gbogbo rẹ̀ ká Ìlú náà sì wà ní ìhámọ́ lábẹ́ ìdọ̀tí títí di ọdún kọkànlá ti ọba Ṣédékíáyà Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹrin, iyàn tí mú ní ìlú tí ó jẹ́ wí pé kò sí oúnjẹ fún àwọn ènìyàn láti jẹ Nígbà náà odi ìlú náà sì fón ká, gbogbo àwọn ọmọ ogun sá lọ ní òru láti ẹnu ọ̀nà bodè láàrin ògiri méjì ní ẹgbẹ́ ọgbà ọba, lára àwọn ará Bábílónì wọ́n sì yí ìlú náà ká Wọ́n sá lọ sí ìkọjá Árábù Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará kalídíà sì lépa ọba, wọ́n sì lée bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jéríkò Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká, Wọ́n sì mú un wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbílà, níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀ Wọ́n sì pa ọmọ Ṣédékáyà níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dèé pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Bábílónì Ní ọjọ́ kèje ní oṣù karùn ún, ní ọdún ìkọkàndínlógún ti Nebukadinésárì ọba Bábílónì, Nebukadinéṣárì olórí ẹ̀sọ́ ti ọba ìjòyè ọba Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì finá sí ilé Olúwa , ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ilé pàtàkì, ó jó wọn níná Gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì, lábẹ́ olórí ti ìjọba ẹ̀sọ́, wó ògiri tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká lulẹ̀ Nebukadinésárí olórí ẹ̀ṣọ́ Kó lọ sí ìgbékùn gbogbo ènìyàn tí ó kù ní ìlú, àti àwọn Ísánsà àti àwọn tí ó ti lo sí ọ̀dọ̀ ọba Bábílón Ṣùgbọ́n olórí ẹ̀sọ́ fí àwọn talákà ènìyàn ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àti orí pápá Àwọn ará Bábílónì fọ́ ọwọ́n idẹ sí túútúú, àti ìjòkòó àti agbada ńlá idẹ tí ó wà nílé Olúwa wọ́n sì kọ́ idẹ wọn sí Bábílónì Wọ́n sì kóo lọ pẹ̀lú àwo ìkòkò ọkọ́, àlùmágàjí fìtílà, síbí àti gbogbo ohun èló idẹ tí wọ́n lò nílé tí wọ́n fi sisẹ́ Olórí ìjọ̀ba ẹ̀sọ́ mu ìfọnná, àti ọpọ́n, èyí tí wọ́n fi wúrà àti Sílifà ṣe lọ Bàbà méjì láti ara ọ̀wọ̀n òkú àti ìjòkòó, tí Ṣólómónì ti ṣe fún ilé Olúwa , ó ju èyí tí a lé wọ́n lọ Ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀wọ̀n gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ ẹsẹ̀ méjìlélógún Olórí Bàbà lórí ọkẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀wọ̀n ọ̀gá ni ìwọ̀n mẹ́rin àti ààbò wọn sì ṣe lọ́sọ́ọ̀ pẹ̀lú iṣe àwọ̀n àti àwọ pòmégránátè tí ó wà lórí ọ̀nà orí gbogbo rẹ̀ yíká, ọ̀wọ̀n mìíràn, pẹ̀lú iṣẹ́ híhun, wọ́n sì kéré Olórí àwọn ọ̀sọ́ sì mú gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn ẹlẹ́wọ̀n Ṣéráíáyà olórí àwọn àlùfáà, Ṣéfáníà àlùfáà ẹni tí ó kù nínú oyè gíga àti àwọn olùṣọ́nà mẹ́ta Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìjòyè tí ó fi sí ipò olórí àwọn ológun ọkùnrin àti àwọn agbà oní ní ìmọ̀ràn ọba Ó sì tún mú akọ̀wé tí ó jẹ́ ìjòyè tí ń to àwọn ènìyàn ilé náà àti mẹ́fà nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú Nebukadínésárì olórí àwọn ẹ̀sọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbílà Níbẹ̀ ní Ríbílà, ní ilẹ̀ Hámátì, ọba sì kọlù wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni Júdà lọ sí oko ẹrú, kúrò láti ilé rẹ̀ Nebukadínésárì ọba Bábílónì ó mú Gédalíàh ọmọ Áhíkámù ọmọ ṣáfánì, láti jọba lórí àwọn ènìyàn tí ó ti fa kalẹ̀ lẹ́yìn ní Júdà Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Bábílónì ti yan Gédálíàh gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gédálíàh ni Mísípà Ísímáélì ọmọ Nétaníàh, Jóhánánì ọmọ Káréà, Séráíáyà ọmọ Tánhúmétì ará Nétófátì, Jásáníáyà ọmọ ara Mákà, àti àwọn ọkùnrin wọn Gédálíà sì búrà láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará káidéà, ó wí pé, Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba Bábílónì, yóò sì dára fún un yín Ní oṣù kèje, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, Ísmáélì ọmọ Nétaníáyà, ọmọ Èlísámà, ẹni tí ó jẹ́ ti ẹ̀jẹ̀ ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá ó sì kọlù Gédálíáyà àti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹwàá ará Júdà àti àwọn ará káídéà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Míspà Nítorí èyí, gbogbo àwọn ènìyàn láti ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, àti pẹ̀lú àwọn olórí ogun, sá lọ si Éjíbítì nítorí ẹ̀rù àwọn ará Bábílónì Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí a lé Jéhóíákínì ọba Júdà kúrò nílú, ní ọdún tí Efili-Méródákì di ọba Bábílónì, ó tú Jéhóíákínì kúrò nínú túbú ní ọjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n oṣú kéjìlá Ó sì sọ̀rọ̀ dáradára ó sì fún ún ní ìjòkòó tí ó ga lọ́lá jùlọ ju gbogbo àwọn ọba tó kù tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì lọ, Bẹ́ẹ̀ ni Jéhóíákínì fi sí ẹ̀gbẹ́ kan àwọn aṣọ́ túbú àti fún gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ tí ó ku oúnjẹ ó ń jẹ, nígbà gbogbo ní orí tabílì ọba Ní ojoojúmọ́ ọba fún Jéhóíákínì ní ohun tí ó yọ̀ǹda nígbà kúgbà gẹ́gẹ́ bí ó tí ń bẹ láàyè Ọ̀tẹ̀ Móábù Jéhórámù ọmọ Áhábù ó sì di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà ní ọdún kejìdínlógún ti Jéhósáfátì ọba Júdà, ó sì jọba fún ọdún méjìlá Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa , ṣùgbọ́n kì í ṣe bí ti ìyá àti bàbá rẹ̀ ti ṣe Ó gbé òkúta ère ti Báálì tí baba rẹ̀ ti ṣe Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi ara mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó ti fi Ísírẹ́lì bú láti dẹ́ṣẹ̀ kò sì yí kúrò lọ́dọ̀ wọn Nísinsìn yìí Mésà ọba Móábù ń sin àgùntàn, ó sì gbọdọ̀ fi fún ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú ọgọ́rún ẹgbẹ̀rùnún ọ̀dọ́ àgùntàn àti pẹ̀lú irú ọgọ́runún ẹgbẹ̀rúnún àgbò Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ikú Áhábù, ọba Móábù ṣọ̀tẹ̀ lórí ọba Ísírẹ́lì Lásìkò ìgbà yìí ọba Jéhórámù jáde kúrò ní Ṣamáríà ó sì yí gbogbo Ísírẹ́lì nípò padà Ó sì ránṣẹ́ yìí sí Jéhóṣáfátì ọba Júdà Ọba Móábù sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi láti lọ bá Móábù jà Èmi yóò lọ pẹ̀lú rẹ, Ó dáhùn Èmi jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà, ènìyàn rẹ bí ènìyàn mi, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ Nípa ọ̀nà wo ni àwa yóò gbà dójukọ wọ́n Ó bèèrè, Lọ́nà ihà Ékírónì, ó dáhùn Bẹ́ẹ̀ ni ọba Isírẹ́lì jáde lọ pẹ̀lú ọba Júdà àti ọba Édómù Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n yíká fún ọjọ́ méje Àwọn ọmọ ogun wọn kò ní omi púpọ̀ fún ara wọn tàbí fún ẹranko tí ó wà pẹ̀lú wọn Kí ni Ọba Ísírẹ́lì kígbe sókè Ṣé Olúwa pè àwa ọba mẹ́tẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Móábù lọ́wọ́ Ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì sì wí pé, Ṣé kò sí wòlíì Olúwa níbí, tí àwa ìbá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ọba Ísírẹ́lì dáhùn pé, Èlíṣà ọmọ Ṣáfátì wà níbí Ó máa ṣábà bu omi sí ọwọ́ Èlíjàh Jèhóṣáfátì wí pé, ọ̀rọ̀ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì àti ọba Édómù sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ Èlíṣà wí fún ọba Ísírẹ́lì pé, Kí ni àwa ní ṣe pẹ̀lú ara wa Lọ sọ́dọ̀ wòlíì bàbá rẹ àti wòlíì ti ìyá rẹ Rárá, ọba Ísírẹ́lì dá a lóhùn, nítorí Olúwa ni ó pe àwa ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Móábù lọ́wọ́ Èlíṣà wí pé, Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pé Olúwa àwọn ọmọ ogun wà láyé, ẹni tí mo ń sìn tí èmi kò bá ní ọ̀wọ̀ fún ojú Jèhósáfátì ọba Júdà, Èmi kò ní wò ó tàbí èmi kì bá ti rí ọ Ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí mú wá fún mi ohun èlò orin olókun Nígbà tí akọrin náà n kọrin, ọwọ́ Olúwa wá sórí Èlíṣà Ó sì wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa sọ Jẹ́ kí àfonífojì kún fún ọ̀gbun Nítorí èyí ni Olúwa wí O kò níí rí afẹ́fẹ́ tàbí òjò, bẹ́ẹ̀ ni àfonífojì yìí yóò kún pẹ̀lú omi, àti ìwọ àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹran yóò mu Èyí jẹ́ ohun tí kò lágbára níwájú Olúwa , yóò sì fi Móábù lé e yín lọ́wọ́ pẹ̀lú Ìwọ yóò sì bi gbogbo ìlú olódí àti gbogbo àgbà ìlú ṣubú Ìwọ yóò sì gé gbogbo igi dáradára ṣubú, dá gbogbo orísun omi dúró, kí o sì pa gbogbo pápá dáradára pẹ̀lú òkúta run Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ní àsìkò ẹbọ ọrẹ, níbẹ̀ ni omí ṣàn láti ọ̀kánkán Édómù! Ilé náà sì kún pẹ̀lú omi Nísinsìnyí gbogbo ará Móábù gbọ́ pé àwọn ọba tí dé láti bá wọn jà Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn, ọmọdé àti àgbà tí ó lè ja ogun wọn pè wọ́n sókè wọ́n sì dúró ní etí ilẹ̀ Nígbà tí wọ́n dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, òòrùn ti tàn sí orí omi náà sí àwọn ará Móábù ní ìkọjá ọ̀nà, omi náà sì pupa bí ẹ̀jẹ̀ Ẹ̀jẹ̀ ni èyí! wọ́n wí pé, Àwọn ọba wọ̀nyí lè ti jà kí wọn sì pa ara wọn ní ìpakúpa Nísinsìn yìí sí àwọn ìkógun Móábù! Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Móábù dé sí ibùdó ti Ísírẹ́lì, àwọn ará Ísírẹ́lì dìde, wọ́n sì kọlù wọ́n títí tí wọ́n fi sálọ Àwọn ará Ísírẹ́lì gbógun sí ilẹ̀ náà wọ́n sì pa Móábù run Wọ́n sì wọ gbogbo ìlú náà olúkúlùkù ènìyàn, wọ́n ju òkúta sí gbogbo ohun dáradára orí pápá títí tí ó fi run Wọ́n sì dá gbogbo orísun omi dúró wọ́n sì gé gbogbo orísun dáradára Kíríháráṣétì nìkan ni wọ́n fi òkúta rẹ̀ sílẹ̀ ní àyè rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ológun pẹ̀lú kanakáná yíká, wọ́n sì kọlù ìlú náà Nígbà tí ọba Móábù rí i wí pé ogun náà le ju ti òun lọ, ó mú idà pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọkùnrin onídà láti jà pẹ̀lú ọba Édómù, ṣùgbọ́n wọn kò yege Nígbà náà ó mú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀, tí kò bá jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba, ó sì fi rú ẹbọ sísun ní orí ògiri ìlú Wọ́n sì bínú lórí Ísírẹ́lì púpọ̀púpọ̀ wọ́n yọ́ kúrò wọ́n sì padà sí ìlú wọn Òróró Obìnrin Opó Ìyàwó ọkùnrin kan láti ara ẹgbẹ́ wòlíì sunkún tọ Èlíṣà wá, Ìránṣẹ́ rẹ ọkọ mi ti kú, ó sì mọ̀ wí pé ó bu ọlá fún Olúwa Ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí onígbèsè rẹ̀ ti ń bọ̀ láti wá kó ọmọ ọkùnrin mi gẹ́gẹ́ bí ẹrú rẹ̀ Èlíṣà dá a lóhùn pé, Báwo ni èmi ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ Sọ fún mi kí ni ìwọ ní ní ilé rẹ Ìránṣẹ́ rẹ kò ní ohunkóhun níbẹ̀ rárá, Ó wí pé, àyàfi òróró kékeré Èlíṣà wí pé, Lọ yíká kí o sì béèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn aládùúgbò fún ìgò òfìfo Má ṣe béèrè fún kékeré Nígbà náà, lọ sí inú ilé kí o sì pa lẹ̀kùn dé ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, dà òróró sínú gbogbo ìgò, gẹ́gẹ́ bí gbogbo rẹ̀ ti kún, kóo sí apákan Ó sì fi sílẹ̀ lẹ́yìn náà ó ti ilẹ̀kùn ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ Wọ́n gbé ìgò wá fún un ó sì ń dà á Nígbà tí gbogbo ìgò náà kún, ó sọ fún ọmọ rẹ̀ pé, Ẹ gbé òmíràn fún mi wá Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, Kò sí ìgò tí ó kù mọ́ Nígbà náà ni òróró kò dà mọ́ Ó sì lọ ó sì lọ sọ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì wí pé, Lọ, ta òróró náà kí o sì san gbésè rẹ Ìwọ àti ọmọ rẹ kí ẹ máa sinmi lórí èyí tí ó kù Ní ọjọ́ kan Èlíṣà lọ sí Ṣúnémù Obìnrin ọlọ́rọ̀ kan sì wà níbẹ̀, ẹni tí ó rọ̀ ọ́ kí ó dúró jẹun Bẹ́ẹ̀ ni nígbàkúgbà tí ó bá ń kọjá lọ, ó máa ń dúró níbẹ̀ láti jẹun Ó sọ fún ọkọ rẹ̀, Mo mọ̀ pé ọkùnrin tí ó máa ń ṣábà wá sí ọ̀dọ̀ wa jẹ́ ọkùnrin mímọ́ Ọlọ́run Jẹ́ kí a ṣe yàrá kékeré kan sórí ilé kí a sì gbé ibùṣùn àti tábìlì oúnjẹ, àga kan àti àtùpà fún un Nígbà náà ó lè dúró níbẹ̀ ní ìgbàkúgbà tí ó bá wá sọ́dọ̀ wa Ní ọjọ́ kan nígbà tí Èlíṣà wá, ó lọ sí orí òkè ní yàrá rẹ̀ ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀ Ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Géhásì pé, Pe ará Ṣúnémù Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀ Èlíṣà wí fún un pé, wí fún un, Ìwọ ti lọ ṣe gbogbo àníyàn iṣẹ́ ìyìnrere fún wa Nísinsìn yìí kí ni a lè ṣe fún ọ   Ṣé alèjẹ́ agbẹnusọ fún ọ ní ọ̀dọ̀ ọba tàbí olórí ogun Kí ni a lè ṣe fún obìnrin yìí Èlíṣà béèrè Géhásì wí pé, Bẹ́ẹ̀ ni, kò ní ọmọ, ọkọ rẹ̀ náà sì tún di arúgbó Nígbà náà Èlíṣà wí pé, Pè é, Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é, ó sì dúró ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà Èlíṣà sọ wí pé, Ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, ìwọ yóò fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọ Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi, nkò fara mọ́ ọn Ma ṣe ṣi ìránṣẹ́ rẹ lọ́nà, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run! Ṣùgbọ́n obìnrin náà lóyún ní ọdún kejì ní àkókò náà, ó bí ọmọ ọkùnrin kan, gẹ́gẹ́ bí Èlíṣà ti sọ fún un Ọmọ náà dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀, ó wà pẹ̀lú àwọn olùkórè Orí mi!, Orí mi! Ó wí fún baba rẹ̀ Baba rẹ̀ sọ fún ìránṣẹ́, Gbé e lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀ Lẹ́yìn ìgbà tí ìránṣẹ́ náà ti gbé e sókè tí ó sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ, ọmọ ọkùnrin náà jókòó sórí ẹsẹ̀ rẹ̀ títí ó fi di ọ̀sán gangan, nígbà náà ó sì kú Ó lọ sí òkè ó sì tẹ́ ọmọ náà lórí ibùsùn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì tilẹ̀kùn, ó jáde lọ Ó pe ọkọ rẹ̀ ó sì wí pé, Jọ̀wọ́ rán ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan kí èmi kí ó lè lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run kíákíá kí n sì padà Kí ni ó dé tí o fi fẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí Ó béèrè Kì í ṣe oṣù túntún tàbí ọjọ́ ìsinmi ó wí pé Gbogbo rẹ̀ ti dára Ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Má a nìṣó má ṣe dẹsẹ̀ dúró dè mí àyàfi tí mo bá sọ fún ọ Bẹ́ẹ̀ ni ó sì jáde wá, ó sì wá sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè Kámẹ́lì Nígbà tí ó sì rí i láti òkèrè, ènìyàn Ọlọ́run sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Géhásì, Wò ó! Ará Ṣúnémù nì! Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, Ṣé o wà dáadáa Ṣé ọkọ rẹ wà dáadáa Ṣé ọmọ rẹ wà dáadáa   Ó wí pé, Gbogbo nǹkan wà dáadáa Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè, ó gbá a ní ẹṣẹ̀ mú Géhásì wá láti wá lé e dànù, ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run wí pé, Fi í sílẹ̀! Ó wà nínú ìpọ́njú, Kíkorò, ṣùgbọ́n Olúwa fi pamọ́ fún mi kò sì sọ ìdí rẹ̀ fún mi Ṣé mo béèrè ọmọ lọ́wọ́ rẹ, Olúwa mi Obìnrin náà wí pé, Ṣé mi ò sọ fún ọ pe kí o, Má ṣe fa ìrètí mi sókè Èlíṣà wí fún Géhásì pé, Ká agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè, mú ọ̀pá mi sí ọwọ́ rẹ kí o sì sáré Tí o bá pàdé ẹnikẹ́ni má ṣe kí i, tí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má ṣe dá a lóhùn, fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ ọkùnrin náà Ṣùgbọ́n ìyá ọmọ náà wí pé, Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láàyè àti gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láàyè, èmi kò níí fi ọ́ sílẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dìde ó sì tẹ̀lé e Géhásì sì ń lọ síbẹ̀ ó sì fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ náà, ṣùgbọ́n kò sí ohùn dídún Bẹ́ẹ̀ ni Géhásì padà lọ láti lọ bá Èlíṣà láti sọ fún un pé, Ọmọ ọkùnrin náà kò tí ì dìde Nígbà tí Èlíṣà dé inú ilé, níbẹ̀ ni òkú ọmọ ọkùnrin náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn Ó sì wọ ilé, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì ó sì gbàdúrà sí Olúwa Nígbà náà ó dé orí ibùsùn, ó sùn sórí ọmọ ọkùnrin náà, ẹnu sí ẹnu, ojú sí ojú, ọwọ́ sí ọwọ́ Gẹ́gẹ́ bí ó ti nà ara rẹ̀ lórí rẹ̀, ara ọmọ náà sì gbóná Èlíṣà yípadà lọ, ó sì rìn padà ó sì jáde wá sínú ilé nígbà náà ó sì padà sí orí ibùsùn ó sì tún nà lé e ní ẹ̀ẹ̀kan sí i Ọmọ ọkùnrin náà sì sín ní ìgbà méje ó sì sí ojú rẹ̀ Èlíṣà sì pe Géhásì ó sì wí pé, Pe ará Súnémù Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ Nígbà tí ó dé, ó wí pé, Gba ọmọ rẹ Ó sì wọlé, ó sì kúnlẹ̀ ṣíwájú ẹṣẹ̀ rẹ̀ ó sì tẹ̀ Orí sílẹ̀ Nígbà náà ó sì mú ọmọ rẹ̀ ó sì jáde lọ Èlíṣà padà sí Gílgálì ìyàn sì wà ní ilẹ̀ náà Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì ṣe ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Gbé ìkòkò ńlá ka iná kí o sì ṣe ọbẹ̀ aláta díẹ̀ fún àwọn ọkùnrin yìí Ọ̀kan lára wọn jáde lọ sí orí pápá láti kó ewébẹ̀ jọ àti láti wá àjàrà ìgbẹ́ Ó sì kó díẹ̀ nínú ẹ̀fọ́ gbọ̀rọ̀ rẹ̀ jọ ó sì ka a kún aṣọ agbádá rẹ̀ Nígbà tí ó padà dé, ó sì gé wọn sínú ìkòkò ọbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí wọ́n ń jẹ Wọ́n da ọbẹ̀ náà jáde fun àwọn ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ oúnjẹ náà, wọ́n sunkún jáde, Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run ikú ń bẹ nínú ìkòkò yìí! Wọn kò sì le jẹẹ́ Èlíṣà sì wí pé, Mú ìyẹ̀fún díẹ̀ wá, Ó sì fi sínú ìkòkò ó sì wí pé, Kí ó sì fi fún àwọn ènìyàn láti jẹ Kò sì sí ohun tí ó léwu nínú ìkòkò náà Ọkùnrin kan wá láti Báálì-Ṣálíṣà, ó sì mú ogún ìṣù àkàrà bárílè, àkàrà tí wọ́n dín láti ara àkọ́kọ́ gbó àgbàdo, àti pẹ̀lú síírì ọkà tuntun Fún àwọn ènìyàn láti jẹ, Èlíṣà wí pé Báwo ni èmi yóò ṣe gbé èyí ka iwájú àwọn ọgọ́ọ̀rún ènìyàn Ìránṣẹ́ rẹ̀ béèrè Ṣùgbọ́n Èlíṣà dá a lóhùn pé, Gbé e fún àwọn ènìyàn láti jẹ, nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ Wọn yóò jẹ yóò sì tún sẹ́kù  Nígbà náà ó gbé e ka iwájú wọn, wọ́n sì jẹ ẹ́, wọ́n sì ní èyí tó ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa Ìwòsàn Námánì Adẹ́tẹ̀ Námánì jẹ́ olórí ogun ọba Árámù Ó jẹ́ ènìyàn ńlá níwájú ọ̀gá rẹ̀, wọ́n sì bu ọlá fún un, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ Olúwa fún wa ní ìṣẹ́gun fún Árámù Ó jẹ́ alágbára, akọni ọkùnrin ṣùgbọ́n, ó dẹ́tẹ̀ Nísinsìnyìí ẹgbẹgbẹ́ láti Árámù ti jáde lọ láti mú ọmọ obìnrin kékeré kan ní ìgbèkùn láti Ísírẹ́lì, ó sì sin ìyàwó Námánì Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samáríà! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ Námánì lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Ísírẹ́lì ti sọ Ní gbogbo ọ̀nà, lọ, ọba Árámù dá a lóhùn pé, Èmi yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí ọba Ísírẹ́lì Bẹ́ẹ̀ ni Námánì lọ, ó sì mú pẹ̀lú rẹ̀ talẹ́ńtì fàdákà mẹ́wàá, ẹgbẹ̀ta ìwọ̀n wúrà àti ìpàrọ̀ aṣọ mẹ́wàá Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì kà pé Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Námánì sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ Bí ọba Ísírẹ́lì ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí àyè padà Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi! Nígbà tí Èlíṣà ènìyàn Ọlọ́run gbọ́ pé ọba Ísírẹ́lì ti ya aṣọ rẹ̀, ó sì rán iṣẹ́ yìí sí i pé Kí ni ó dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya Jẹ́ kí ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi Òun yóò sì mọ̀ pé wòlíì wà ní Ísírẹ́lì Bẹ́ẹ̀ ni Námánì sì lọ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀ àti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ilé Èlíṣà Èlíṣà rán ìránṣẹ́ láti lọ sọ fún un pé, Lọ, wẹ̀ ara rẹ ní ìgbà méje ní odò Jọ́dánì, ẹran ara rẹ yóò sì tún padà bọ̀ sípò, ìwọ yóò sì mọ́ Ṣùgbọ́n Námánì lọ pẹ̀lú ìbúnú ó sì wí pé, Mo lérò pé yóò sì dìde jáde wá nítòótọ́ sí mi, yóò sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run, fi ọwọ́ọ rẹ̀ lórí ibẹ̀ kí ó sì wo ẹ̀tẹ̀ mi sàn Ábánà àti Fápárì, odò Dámásíkù, dára ju gbogbo omi Ísírẹ́lì lọ Ṣé èmi kò le wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́ Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà, ó sì lọ pẹ̀lú ìrunú Ìránṣẹ́ Námánì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, Baba mi, tí wòlíì bá ti sọ fún ọ láti ṣe ohun ńlá kan, ṣé ìwọ kì bá ti ṣe, mélòómélòó nígbà náà, nígbà tí ó sọ fún ọ pé, Wẹ̀ kí o sì mọ́! Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jọ́dánì ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré Nígbà náà Námánì àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ padà lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run Ó sì dúró níwájú rẹ̀ ó sì wí pé, Nísinsìnyí èmi mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé àyàfi ní Ísírẹ́lì nìkan Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn láti ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ Wòlíì náà dáhùn pé, Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, ẹni tí mo ń sìn, èmi kò ní gba ohun kan, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Námánì rọ̀ ọ́ láti gbàá, ó kọ̀ Tí o kò bá ní gba, Námánì wí pé, Jọ̀wọ́ jẹ́ kí èmi, ìránṣẹ́ rẹ fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹrù ẹrùpẹ̀ ìbaka méjì, nítorí láti òní lọ ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rú ẹbọ sísun àti rúbọ sí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́run mìíràn ṣùgbọ́n Olúwa Ṣùgbọ́n kí Olúwa kí ó dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún nǹkan yìí Nígbà tí ọ̀gá mi wọ inú ilé Rímónì láti fi orí balẹ̀ tí ó sì fi ara ti ọwọ́ mi tí mo sì tẹ ara mi ba pẹ̀lú níbẹ̀ Nígbà tí èmi tẹ ara mi ba ní ilé Rímónì, kí Olúwa dáríji ìránṣẹ́ rẹ fún èyí Èlíṣà wí pé, Má a lọ ní àlàáfíà Lẹ́yìn ìgbà tí Námánì tí rin ìrìnàjò tí ó jìnnà, Géhásì, ìránṣẹ́ Èlíṣà ènìyàn Ọlọ́run, ó wí fún ara rẹ̀ pé, Ọ̀gá mi jẹ́ ẹni tí ó rọ̀ lórí Námánì, ará Árámù, nípa pé kò gba ohunkóhun ní ọwọ́ rẹ̀ ohun tí ó mú wá, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, èmi yóò sá tẹ̀lé e èmi yóò sì gba ohun kan ńi ọwọ́ rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni Géhásì sáré tẹ̀lé Námánì Nígbà tí Námánì rí i tí ó ń sáré tẹ̀lé e, ó sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ̀ Ṣé gbogbo nǹkan wà dáadáa ó béèrè Gbogbo nǹkan wà dáadáa, Géhásì dá a lóhùn Ọ̀gá mi rán mi láti sọ wí pé, Àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin méjì láti ọ̀dọ̀ ọmọ wòlíì wọ́n ṣẹ̀ ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi láti orí òkè ìlú ti Éfúráímù Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn fàdákà àti ìpàrọ̀ aṣọ méjì   Námánì wí pé, Ní gbogbo ọ̀nà, mú ẹ̀bùn méjì Ó sì rọ Géhásì láti gbà wọ́n, ó sì di ẹ̀bùn méjì náà ti fàdákà ní inú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì, wọ́n sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ Géhásì Nígbà tí Géhásì wá sí ilẹ̀ gíga, ó sì mú nǹkan náà lọ́dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì gbé wọn kúrò ní ilé, ó sì rán ọkùnrin náà jáde ó sì lọ Nígbà náà ó sì wọlé wá ó sì dúró níwájú ọ̀gá rẹ̀ Èlíṣà Níbo ni o ti wà Géhásì Èlíṣà bèèrè Ìránṣẹ́ rẹ kò lọ sí ibìkan kan Géhásì dá a lóhùn Ṣùgbọ́n Èlíṣà wí fún un pé, Ẹ̀mí mi kò ha wà pẹ̀lú rẹ nígbà tí ọkùnrin náà sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ Ṣé àsìkò tí ó yẹ láti gba owó nìyìí, tàbí láti gba aṣọ, ọgbà-ólífì, ọgbà àjàrà, àgùntàn, màlúù tàbí ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin Ẹ̀tẹ̀ Námánì yóò rọ̀mọ́ ọ àti sí irú ọmọ rẹ títí láé Nígbà náà Géhásì kúrò níwájú Èlíṣà, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú Orí Àáké Fò Lójú Omi Àwọn ọmọ wòlíì sọ fún Èlíṣà pé, Wò ó, ní ibi tí a ti pàdé pẹ̀lú rẹ, ó kéré fún wa Jẹ́ kí àwa kí ó lọ sí Jọ́dánì, ní ibi tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti le rí ọ̀pá kan, jẹ́ kí àwa kí ó kọ́lé síbẹ̀ fún wa láti gbé Ó sì wí pé, lọ Nígbà náà ni ọ̀kan lára wọn wí pé, Ṣé ìwọ kò ní jọ̀wọ́ wa pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ Èmi yóò lọ, Èlíṣà dá a lóhùn Ó sì lọ pẹ̀lú wọn Wọ́n sì lọ sí Jọ́dánì wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gé igi Bí ọ̀kan ṣe gé igi náà, àáké irin náà bọ́ sínú omi, ó kí gbe sókè pé, o! Olúwa mi, mo yá a ni Ènìyàn Ọlọ́run sì béèrè pé, Níbo ni ó bọ́ sí Nígbà tí ó fi ibẹ̀ hàn án, Èlíṣà ge igi kan ó sì jù ú síbẹ́, ó sì mú irin náà fò lójú omi Ó wí pé, Gbé e jáde Nígbà náà ọkùnrin náà na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú un Nísinsìn yìí ọba Árámù ó wà ní ogun pẹ̀lú Ísírẹ́lì ó sì bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ gbérò, ó wí pé Èmi yóò ṣe ibùdó mi sí ibí yìí nínú èyí náà àti bí ibí yìí Ènìyàn Ọlọ́run rán iṣẹ́ sí ọba Ísírẹ́lì, kíyèsí ara láti kọjá ní ibẹ̀ yẹn, nítorí pé ará Árámù wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ síbẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì wo ibi tí ènìyàn Ọlọ́run náà fi hàn, ní ẹ̀ẹ̀kan sí i Èlíṣà kìlọ̀ fún ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó wà lórí sísọ ní ibẹ̀ Èyí mú ọba Árámù bínú Ó pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Ṣé ìwọ kò ní sọ fún un èwo nínú wa ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọba Ísírẹ́lì Kò sí ọ̀kan nínú wa, Olúwa ọba mi, ọ̀kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí pé, ṣùgbọ́n Èlíṣà, wòlíì tí ó wà ní Ísírẹ́lì, sọ fún ọba Ísírẹ́lì ọ̀rọ̀ gangan tí ó sọ nínú yàrá rẹ̀ Lọ, kí ẹ lọ wo ibi tí ó wà, ọba pa á láṣẹ, Kí èmi kí ó lè rán ènìyàn láti lọ mú un wá Ìròyìn padà wá Ó wà ní Dótanì Nígbà náà ó rán àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ àti ogun ńlá tí ó le síbẹ̀ Wọ́n sì lọ ní alẹ́ wọ́n sì yí ìlú náà ká Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká Yé è, Olúwa mi, kí ni kí àwa kí ó ṣe ìránṣẹ́ náà béèrè Má ṣe bẹ̀rù, wòlíì náà dáhùn, Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa, wọ́n pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ Èlíṣà sì gbàdúrà, Olúwa , la ojú rẹ̀ kí ó ba à lè ríran Nígbà náà Olúwa la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì wò, ó sì rí òkè ńlá tí ó kún fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ iná gbogbo yí Èlíṣà ká Bí àwọn ọ̀tá ṣe ń sọ̀kalẹ̀ wá níwájú rẹ, Èlíṣà gbàdúrà sí Olúwa pé Bu ìfọ́jú lu àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Olúwa sì se gẹ́gẹ́ bí Èlíṣà ti béèrè Èlíṣà sọ fún wọn pé Èyí kì í ṣe ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ni èyí kì í ṣe ìlú náà Tẹ̀lé mi, èmi yóò mú u yín lọ sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin tí ẹ̀yin ń wá Ó sì sìn wọ́n lọ sí Samáríà Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n wọ ìlú náà, Èlíṣà wí pé, Olúwa , la ojú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kí wọn kí ó lè ríran Nígbà náà Olúwa la ojú wọn, wọ́n sì ríran, wọ́n sì wà níbẹ̀, nínú Samáríà Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì rí wọn, ó béèrè lọ́wọ́ Èlíṣà pé, Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n, Baba mi Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n Má se pa wọ́n, ó dáhùn Ṣé ìwọ yóò pa àwọn ọkùnrin tí ìwọ mú pẹ̀lú idà rẹ tàbí ọrun rẹ Gbé oúnjẹ àti omi ṣíwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ kí wọn sì mu, nígbà náà kí wọn padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn Bẹ́ẹ̀ ni ó pèṣè àṣè ńlá fún wọn, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ tí wọ́n mu, ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn Bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ́ láti Árámù dáwọ́ ìgbógun ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì dúró Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ni Bẹni-Hádádì ọba Árámù kó gbogbo àwọn ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì yan sókè wọ́n sì dúró ti Samáríà Ìyàn ńlá sì mú ní ìlú náà wọ́n dúró tìí tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní ọgọ́ọ̀rùnún ìwọ̀n fàdákà àti ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n kábù imí ẹyẹlé, fún ìwọ̀n fàdákà márùn ún Gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì ti ń kọjá lọ lórí odi, obìnrin kan sunkún sí I pé, Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa ọba mi! Ọba sì dá a lóhùn pé, Tí Olúwa kò bá ràn ọ́ lọ́wọ́, níbo ni èmi ti lè rí ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ Láti inú ilé ìpakà Láti inú ibi ìfúntí Nígbà náà ó béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà pé, Kí ni ó ṣẹlẹ̀ Obìnrin náà dáhùn pé, Obìnrin yìí wí fún mi pé, Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ ẹ́ lónìí, ní ọ̀la àwa yóò jẹ ọmọkùnrin tèmi Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ọmọkùnrin mi a sì jẹ ẹ́ Ní ọjọ́ kejì mo wí fún un pé, Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ, ṣùgbọ́n ó ti gbé e pamọ́ Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ obìnrin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya Gẹ́gẹ́ bí ó sì ti ń kọjá lọ sí orí odi, àwọn ènìyàn wò ó níbẹ̀ ní abẹ́, ó ní aṣọ ọ̀fọ̀ ní ara rẹ̀ Ó sì wí pé, Kí Olúwa kí ó fi ìyà jẹ mí, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ dájúdájú, pé orí ọmọkùnrin Èlíṣà ọmọ Sáfátì kì ó wà ní ọrùn rẹ̀ ní òní! Nísinsìnyí Èlíṣà jókòó ní ilé rẹ̀ àwọn àgbààgbà náà jókòó pẹ̀lú rẹ̀ Ọba sì rán oníṣẹ́ ṣíwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó tó dé ibẹ̀, Èlíṣà sọ fún àwọn àgbààgbà pé, Ṣé èyin kò rí bí apànìyàn ti ń rán ẹnìkan láti gé orí mi kúrò Ẹ wò ó, nígbà tí ìránṣẹ́ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn kí ẹ sì dì í mú ṣinṣin nítorí rẹ̀, kì í ṣe ìró ẹsẹ̀ ọ̀gá rẹ̀ wà lẹ́yìn rẹ Nígbà tí ó sì ń sọ̀rọ̀ sí wọn, ìránṣẹ́ náà sọ̀kalẹ̀ wá bá a Ọba náà sì wí pé, Ibi yìí láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni Kí ni ó dé tí èmi yóò fi dúró de Olúwa sí i Ìgbógun Tì Náà Kúrò Èlíṣà wí pé, Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Èyí ni ohun tí Olúwa sọ Ní àsìkò yìí ní ọ̀la, a ó ta òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúná kan ní ṣékélì kan àti méjì òṣùwọ̀n ọkà fún ṣékélì kan ní ẹnu bodè Samáríà Ìjòyè kan ẹni tí ọwọ́ ọba ń fi ara tì dáhùn wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, Ẹ wòó, tí Olúwa bá tilẹ̀ sí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, ṣé èyí lè rí bẹ́ẹ̀ Ìwọ yóò rí i pẹ̀lú ojú rẹ, Èlíṣà dáhùn, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ nǹkankan lára rẹ̀! Nísinsìn yìí àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan wà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀ ní ẹnu àbáwọlé ibodè ìlú Wọ́n wí fún olúkúlùkù pé, kí ni ó dé tí àwa yóò fi jókòó síbí títí àwa yóò fi kú Tí àwa bá wí pé, Àwa lọ sí ìlú, ìyàn wà níbẹ̀, àwa yóò sì kú Tí àwa bá dúró níbí, a máa kú, ǹjẹ́ Nísinsìnyí ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibùdó ti àwọn ará Síríà kí àwa kí ó sì tẹríba Bí wọ́n bá dá wa sí, àwa yóò yè, tí wọ́n bá sì pa wá, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò kú Ní àfẹ̀mójúmọ́ wọ́n dìde wọ́n sì lọ sí ibùdó àwọn ará Síríà Nígbà tí wọ́n dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó náà, kò sí ọkùnrin kan níbẹ̀, Nítorí tí Olúwa jẹ́ kí àwọn ará Síríà gbọ́ ìró kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin àti ogun ńlá, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, Ẹ wò ó, ọba Ísírẹ́lì ti bẹ ogun àwọn Hítì àti àwọn ọba Ígíbítì láti dojúkọ mú u wá! Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dìde wọ́n sì sálọ ní àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n sì fi àgọ́ wọn sílẹ̀ àti ẹṣin wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Wọ́n sì fi ibùdó sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà, wọ́n sì sálọ fún ẹ̀mí wọn Nígbà tí àwọn ọkùnrin tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó wọ́n sì wọ inú ọ̀kan nínú àgọ́ náà Wọ́n jẹ wọ́n sì mu, wọ́n sì kó fàdákà, wúrà àti ẹ̀wù, wọ́n sì lọ Wọ́n sì wọ àgọ́ mìíràn lọ, wọ́n kó àwọn nǹkan láti ibẹ̀ wọ́n sì kó wọn pamọ́ pẹ̀lú Nígbà náà wọ́n wí fún ara wọn pé, Àwa kò ṣe ohun rere Oni yìí jẹ́ ọjọ́ ìròyìn rere àwa si paamọ́ ara wa Tí àwa bá dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́, ìjayà yóò jẹ́ ti wa Ẹ jẹ́ kí a lọ ní ẹ̀ẹ̀kan kí a lọ ròyìn èyí fún àwọn ilé ọba Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì lọ wọ́n sì pe àwọn oníbodè wọ́n sì wí fún wọn pé, Àwa lọ sí ibùdó àwọn ará Síríà kò sì sí ọkùnrin kankan níbẹ̀ tàbí ohùn ènìyàn kan àyàfi ẹṣin tí a so àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn àgọ́ náà sì wà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà Àwọn aṣọ́bodè náà pariwo ìròyìn náà, wọ́n sì sọ nínú ààfin Ọba sì dìde ní ùru ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Èmi yóò ṣọ fún yín ohun tí àwọn ará Ṣíríà tí ṣe fún wa Wọ́n mọ̀ wí pé ebi ń pa wá bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ti kúrò ni ibùdó láti sá pamọ́ sí ẹ̀gbẹ́ ilé, wọ́n rò wí pé, Wọn yóò jáde lóòtọ́, nígbà náà àwa yóò mú wọn ní ààyè àwa yóò yí wọ inú ìlú lọ   Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dáhùn pé, Mú ọkùnrin díẹ̀ mú márùnún lára àwọn ẹsin tí wọ́n fi sílẹ̀ nínú ìlú Ìwà wọn yóò dà bí gbogbo àwọn ará Ísírẹ́lì tí ó kù níbẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóò dà bí gbogbo àwọn Ísírẹ́lì, yìí nìkan tí a run Bẹ́ẹ̀ ni ẹ jẹ́ kí a rán wọn lọ láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan kẹ̀kẹ́ méjì pẹ̀lú ẹsin wọn, ọba sì ránsẹ́ tọ ogun àwọn ará Síríà lẹ́yìn ó pàṣẹ fún àwọn awakọ̀ pé, Ẹ lọ kí e lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ Wọ́n sì tẹ̀lé wọn títí dé Jọ́dánì, wọ́n sì rí gbogbo ọ̀nà kún fún agbádá pẹ̀lú ohun èlò tí ará àwọn Ṣíríà gbé sọnù ní yàrá wọn Ìránsẹ́ náà padà ó sì wá sọ fún ọba Nígbà náà àwọn ènìyàn jáde lọ ìkógun ní ibùdó àwọn ará Ṣíríà Bẹ́ẹ̀ ni òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kan ni wọ́n tà fún Sẹ́kẹ́lì kan, àti òsùnwọ̀n báálì méjì ní Ṣékélì kan, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nísìn yìí ọba sì mú ìjòyè náà lórí ẹni tí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ tì ní ìkáwọ́ ẹnu ibodè, àwọn ènìyàn sì tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ẹnu ibodè Ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti ṣọ tẹ́lẹ̀ nígbà tí ọba sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ Ó sì ti sẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyan Ọlọ́run ti ṣọ fún ọba Ní àsìkò yìí ní ọ̀la, òsùnwọ̀n ìyẹ̀fun ni a ó ta nì Ṣékélì kan àti òsùnwọ̀n méjì báálì ní Ṣékélì kan ní ẹnu ọ̀nà ibodè Ṣamáríà Ìjòyè náà ti wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, Wò ó, kó dà ti Olúwa bá sí fèrèsé ní ọ̀run, ṣé èyí lè ṣẹlẹ̀ Ènìyàn Ọlọ́run sì ti dáhùn pé, kìkì ojú rẹ ni ìwọ yóò fi rí i, Ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ ọ̀kan kan lára rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí fún un gẹ́lẹ́, nítorí tí àwọn ènìyàn tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ẹnu ibodè, ó sì kú Obìnrin Ará Ṣúnámù Gba Ilẹ̀ Rẹ̀ Padà Nísin yìí, Èlíṣà wí fún obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin jí pàdà sáyé pé, jáde lọ pẹ̀lú ìdílé rẹ kí o sì lọ dúró fún ìgbà díẹ̀ ní ibíkíbi tí o bá le dúró sí, nítorí Olúwa ti pàṣẹ ìyàn ní ìlú tí yóò lò tó ọdún méje Obìnrin náà tẹ̀ ṣíwájú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ti sọ Òun àti ìdílé rẹ̀ sá lọ, wọ́n sì dúró ní ilé àwọn ará Fílístínì fún ọdún méje Ní ẹ̀yìn ọdún méje ó sì padà wá láti ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì ó sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba láti lọ bẹ̀ẹ́ fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀ Ọba sì ń sọ̀rọ̀ sí Géhásì, ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pé, Sọ fún mi nípa gbogbo ohun ńlá tí Èlísà ti ṣe Bí Gèhásì ti ń sọ bí tí Èlíṣà ṣe jí òkú di alàyè, obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tí Èlíṣà ti dá padà sí ayé wá láti bẹ ọba fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀ Gèhásì sì wí pé, Obìnrin náà nì yí Olúwa mi ọba, ọmọkùnrin rẹ náà nìyí tí Èlísà ti jí dìde sí ayé Ọba bèèrè lọ́wọ́ obìnrin náà nípa rẹ̀, ó sì sọ fún un Ó sì yan ìjòyè kan fún ún fún ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì wí fún un pé, Ẹ fún un padà gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ tirẹ̀, àti pẹ̀lú gbogbo èrè ilé rẹ̀ fún ún láti ọjọ́ tí ó ti kúrò ní ìlú títí di àsìkòyí Èlíṣà lọ sí Dámásíkù, Bẹni-Hádádì ọba Ṣíríà ń ṣe àìsàn Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba pé, Ènìyàn Ọlọ́run ti wá láti gbogbo ọ̀nà òkè síbí, ó sì wí fún Hásáélì pé, Mú ẹ̀bùn kan pẹ̀lú rẹ láti lọ pàdé ènìyàn Ọlọ́run Kí o sì béèrè Olúwa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn yìí Hásáélì lọ láti pàdé Èlísà, ó mú lọ pẹ̀lú rẹ̀ ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí ogójì ẹrù ìbákasìẹ tí gbogbo ìní tí ó dára jù fún wíwò ti Dámásíkù, ó sì wọlé lọ ó sì dúró níwájú rẹ̀, ó sì wí pé, Ọmọ rẹ Bénhádádì ọba Ṣíríà rán mi láti béèrè pé, Ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn mi yìí   Èlíṣà da á lóhùn pé, Lọ kí o lọ sọ fún un pé, Ìwo ìbá sàn ní tòótọ́ ṣùgbọ́n Olúwa ti fi hàn mí pé nítòotọ́ òun yóò kú Ó sì ranjú mọ́ ọn pẹ̀lú àtẹjúmọ́ gidigidi títí tí ojú fi ti Hásáélì Nígbà náà ènìyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún Kí ni ó dé tí Olúwa mi fi ń sunkún Hásáélì bèèrè Nítorí pé èmi mọ ibi tí ìwọ yóò ṣe sí Ísírẹ́lì, ó sì dáhùn pé, Ìwọ yóò fi iná si odi agbára wọn, ìwọ yóò, pa àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú idà, ìwọ yóò kọlù àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, ìwọ ó sì fọ́ wọn túútúú, ìwọ o sì la inú àwọn aboyún wọn Hásáélì sì wí pé Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ, ajá lásán làsàn yóò ṣe ṣe irú nǹkan ńlá bẹ́ẹ̀ Olúwa ti fi hàn mí pé ìwọ ni yóò jẹ ọba síríà, Èlíṣà dá a lóhùn Nígbà náà Hásáélì fi Èlíṣà sílẹ̀ ó sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ Nígbà tí Bẹnihádádi bèèrè, Kí ni ohun tí Èlíṣà sọ fún ọ Hásáélì dá a lóhùn, Ó sọ fún mi wí pé ìwọ yóò sàn nítòótọ́ Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì ó mú aṣọ tí ó nípọn, ó sì kì í bọ inú omi ó sì tẹ̀ẹ́ sí ojú ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú Nígbá náà Hásáélì sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ní ọdún karùn-ún ti Jórámù ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì, nígbà tí Jéhóṣáfátì jẹ́ ọba Júdà, Jéhórámù ọmọ Jéhóṣáfátì bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Júdà Ó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba Ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́jọ Ó sì rìn ní ọ̀nà ọba Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti lọ, nítorí ó fẹ́ ọmọbìnrin Áhábù ó sì ṣe ohun búburú níwájú Olúwa Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ̀ Dáfídì Olúwa kò fẹ́ pa Júdà run, ó ti ṣèlérí láti ṣètọ́jú ìmọ́lẹ́ fún Dáfídì àti àwọn ilé rẹ̀ títí láéláé Ní àsìkò Jéhórámù, Édómù ṣọ̀tẹ̀ lórí Júdà, ó sì jẹ́ ọba fúnrararẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni Jéhórámù lọ sí Ṣáírì pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ rẹ̀ Àwọn ará Édómù sì yí i ká àti kẹ̀kẹ́ àwọn olórí wọn, ṣùgbọ́n ó dìde dúró ní òru àwọn ogun rẹ̀ síbẹ̀ síbẹ̀, sá padà lọlé Títí ó fi di òní, Édómù wà nínú ọ̀tẹ̀ lórí Júdà, Líbinà ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò kan náà Gẹ́gẹ́ bí fún iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Jórámù, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà Jórámù sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú Dáfídì, Áhásáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Ní ọdún méjìlá Jórámù ọmọkùnrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì, Áhásáyà ọmọkùnrin Jéhórámù ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀ Áhásáyà jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba Ó sì jọba ní ọdún kan ní Jérúsálẹ́mù Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Átalíàh, ọmọbìnrin Ómírìe ọba Ísírẹ́lì Nígbà tí ó rin ọ̀nà ilé Áhábù ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa , gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe, nítorí ó tan nípa ìgbéyàwó sí ìdílé Áhábù Áhásáyà sì lọ pẹ̀lú Jórámù ọmọ Áhábù lọ sí ogun lórí Hásáélì ọba Árámù ní Ramoti-Gílíádì Àwọn ará Ṣíríà ṣẹ́ Jórámù lẹ́sẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ọba Jórámù padà sí Jéṣérẹ́lì láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí ará Síríà ti jẹ níyà lórí rẹ̀ ní Rámò ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Hásáélì ọba Árámù Nígbà náà Áhásáyà ọmọ Jéhórámù ọba Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jésérẹ́lì láti lọ wo Jórámù ọmọ Áhábù nítorí tí ó fi ara pa A fi àmì òróró yàn Jéhù ní ọba Ísírẹ́lì Wòlíì Èlíṣà fi àṣẹ pe ọkùnrin kan láti ẹgbẹ́ àwọn wòlíì, ó sì wí fún un pé, Ki agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè rẹ, gba ṣágo kékeré òróró yìí pẹ̀lú rẹ, kí o sì lọ sí Ramoti-Gílíádì Nígbà tí o bá dé bẹ̀, wá Jéhù ọmọ Jéhóṣáfátì, ọmọ Mímísì kiri Lọ sí ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀, mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, kí o sì mú un wọ inú yàrá lọ́hùn ún lọ Nígbà náà, mú ṣágo kékeré yìí, kí o sì da òróró náà lé e lórí, kí o sì wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí Èmi fi àmì òróró yàn Ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì Nígbà náà, sí ìlẹ̀kùn, kí o sì sáré Má ṣe jáfara! Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wòlíì náà lọ sí Ramoti-Gílíádì Nígbà tí ó dé, ó rí àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n jókòó papọ̀ Èmi ní iṣẹ́ fún ọ, olórí, Ó wí Fún èwo nínú wa Jéhù béèrè Fún ọ, Alákóso, Ó dáhùn Jéhù dìde sókè, ó sì wọ inú ilé lọ Nígbà náà, wòlíì náà da òróró náà sórí Jéhù ó sì wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn Olúwa Ísírẹ́lì Kí ìwọ kí ó pa ilé Áhábù ọ̀gá à rẹ̀ run, Èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa tí a ta sílẹ̀ látọwọ́ ọ Jésébélì Gbogbo ilé Áhábù yóò ṣègbé Èmi yóò gé e kúrò láti orí Áhábù gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó gbẹ̀yìn ni Ísírẹ́lì, ẹrú tàbí òmìnira Èmi yóò ṣe ilé Áhábù gẹ́gẹ́ bí ilé Jéróbóhámù ọmọ Nábátì àti ilé Bááṣà ọmọ Áhíjà Fún Jésébélì, ajá ni yóò jẹ ẹ́ ní oko Jésírẹ́lì, kò sì sí ẹni tí yóò sin òkúrẹ̀   Nígbà náà ó sí ìlẹ̀kùn, ó sì sálọ Nígbà tí Jéhù jáde lọ bá àwọn ọgbà ìjòyè e rẹ̀, ọ̀kan nínú wọn sì bi í pé, Ṣé gbogbo nǹkan dára Kí ni ó dé tí aṣiwèrè fi tọ̀ ọ́ wá, Ìwọ mọ ọkùnrin náà àti irú nǹkan tí ó ń sọ, Jéhù fèsì Ìyẹn kì í ṣe òótọ́! Wọ́n wí Ṣọ fún wa Jéhù wí, Èyí ni ohun tí ó sọ fún mi Èyí ni ohun tí Olúwa wí Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì   Wọ́n ṣe gírì, wọ́n sì mú agbádá a wọn, wọ́n sì tàn wọ́n sí abẹ́ rẹ̀ ní órí àtẹ̀gùn Nígbà náà, wọ́n fọn ipè, wọ́n sì kígbe, Jéhù jẹ ọba! Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù ọmọ Jéhósáfátì, ọmọ Nímsì, dìtẹ̀ sí Jórámù Jéhù wí pé, Tí èyí bá jẹ́ ọ̀nà tí ò ń rò, má ṣe jẹ́ kí ẹnìkankan kí ó yọ jáde nínú ìlú ńlá láti lọ sọ ìròyìn náà ní Jéṣérẹ́lì Nígbà náà ó wọ inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì gùn ún lọ sí Jésérẹ́lì, nítorí Jórámù ń sinmi níbẹ̀ àti ọba Áhásáyà tilọ láti lọ wò ó Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jésérẹ́lì, rí ọ̀wọ́-ogun Jéhù tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀ Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan, Jórámù pa á láṣẹ Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà   Ọkùnrin ẹlẹ́ṣin náà, lọ láti lọ bá Jéhù ó sì wí pé, Èyí ni ohun tí ọba wí Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà   Kí ni ìwọ ní ṣe pẹ̀lú àlàáfíà Jéhù sì dáhùn Ṣubú sími lẹ́yìn Olùṣọ́ náà sì wí fún un pé, Ìránṣẹ́ náà ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ Bẹ́ẹ̀ ni, ọba rán ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kejì, Nígbà náà ó wá sí ọ̀dọ̀ wọn, ó wí pé, Èyí ni ohun tí ọba sọ Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà Jéhù dáhùn, Ṣúbu sími lẹ́yìn Olùṣọ́ náà sì fi sùn Ó ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ pẹ̀lú Wíwá rẹ̀ sì dàbí ti Jéhù ọmọ Nímsì, ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti aṣiwèrè Fi ìwọ̀ kọ́ kẹ̀kẹ́ ogun mi Jórámù pa á láṣẹ Àti nígbà tí a fi kọ́, Jórámù ọba Ísírẹ́lì àti Áhásáyà ọba Júdà, gun kẹ̀kẹ́ lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ogun tirẹ̀, láti lọ bá Jéhù Wọ́n bá a pàdé ní ibi oko tí ó ti jẹ́ ti Nábótì ará Jéṣírẹ́lì Nígbà tí Jórámù rí Jéhù, ó béèrè pé, Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà, Jéhù Báwo ni àlàáfíà yóò ṣe wà, Jéhù dáhùn, Ní ìwọ̀n ìgbà tí gbogbo ìbọ̀rìṣà àti iṣẹ́ àjẹ́ ti mọ̀mọ́ rẹ Jésébélì di púpọ̀ Jórámù yípò padà, ó sì sá lọ ó sì ń pe Áhásáyà, ó ṣe ìwà àrékérekè, Áhásáyà! Nígbà náà, Jéhù fa ọrun rẹ̀, ó sì yin Jórámù láàárin èjìká méjèèjì Ọfà náà sì wọ inú ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀ láti orí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ Jéhù sọ fún Bídíkárì, balógun kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ pé, Gbé e sókè kí ó sì jù ú sí orí pápá tí ó jẹ́ ti Nábótì ará Jésérẹ́lì Rantí bí èmi àti ìwọ ti ń gun kẹ̀kẹ́ papọ̀ lẹ́yìn Áhábù bàbá à rẹ nígbà tí Olúwa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Nábótì pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni Olúwa wí Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa Nígbà tí Áhásáyà ọba, Júdà rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Bẹti-Hágánì Jéhù sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, Pa á pẹ̀lú! Wọ́n sá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Gúrì lẹ́bà a Íbíléámù, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Mégídò, ó sì kú síbẹ̀ Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jérúsálẹ́mù, ó sì sin ín pẹ̀lú, bàbá a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dáfídì Nígbà náà Jéhù lọ sí Jésérẹ́lì Nígbà tí Jésébélì gbọ́ nípa rẹ̀, ó kun ojú u rẹ̀, ó to irun rẹ̀, ó sì wò jáde láti ojú fèrèsé Bí Jéhù ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, Ṣé ìwọ wá lálàáfíà, Símírì, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi Ta ni Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀ Jéhù sọ wí pé, Gbé e jùsílẹ̀ wọ́n sì jù ú sílẹ̀! Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn Jéhù wọ inú ilé lọ, ó jẹ ó sì mu Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú, Ó wí, Kí o sì sin-ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́ Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde lọ láti lọ sin-ín, wọn kò rí nǹkankan àyàfi agbárí i rẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ ọ rẹ̀ méjèèjì Wọ́n padà lọ sọ fún Jéhù, ẹni tí ó wí pé, Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà ará Tíṣíbì wí pé Ní orí oko Jésérẹ́lì ni àwọn ajá yóò ti jẹ ẹran ara Jésébélì Òkú Jésébélì yóò dàbí ohun ẹ̀gbin ní orí oko Jésérẹ́lì, débi pé, ẹnikẹ́ni kì yóò lè sọ pé, Jésébélì ni èyí   Mímú Kí Ìpè Àti Yíyàn Ẹni Dájú Símónì Pétérù, ìránṣẹ́ àti Àpósítélì Jésù Kírísítì, Sí àwọn tí ó gba irú iyebíye igbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú wá nínú òdodo Ọlọ́run wa àti ti Jésù Kírísítì Olùgbàlà Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jésù Olúwa wá Agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí í ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀ Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wá pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábàápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yín bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsinmi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere Àti àìrékọjá kún ìmọ̀ àti sùúrù kún àìrékọjá àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì Nítorí bí ẹ̀yín bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jésù Kírísítì Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́ Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsinmi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò subú Nítorí bayìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kírísítì Nítorí náà, èmi ó máa rán yin létí àwọn nǹkan wọ̀nyìí nígbàgbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti mọ̀ wọ́n, tí ẹsẹ̀ yín sì múlẹ̀ nínú òtítọ́ tí ẹ ní báyìí Èmi sì rò pé ó tọ́ láti máa mú wọn wá sí ìrántí yín, níwọ̀n ìgbà tí èmí ba ń bẹ nínú àgọ́-ara yìí Bí èmi ti mọ̀ pé, bíbọ́ àgọ́-ara mi yìí sílẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, àní bí Olúwa wa Jésù Kírísítì ti fi hàn mí Èmi o sì máa ṣaápọn pẹ̀lú, kí ẹ̀yin lè máa rántí nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo lẹ́yìn ikú mi Nítorí kì í ṣe bí ẹni tí ó ń tọ ìtàn asán lẹ́yìn tí a fí ọgbọ́nkọ́gbọ́n là sílẹ̀, nígbà tí àwa sọ fún yín ní ti agbára àti wíwá Jésù Kírísítì Olúwa, ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí Ọlá-ńlá Rẹ̀ ni àwa jẹ́ Nítorí tí Ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, nígbà tí irú ohùn yìí fọ̀ sí i láti inú ògo ńlá náà wá pé, Èyí ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi Àwa pẹ̀lú sì gbọ́ ohun yìí tí ó ti ọ̀run wá nígbà tí àwa wà pẹ̀lú rẹ̀ ní orí òkè mímọ́ náà Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlìí dunjúdunjú síi, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsí gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ́ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí ẹ ní òye yìí pé kò sí àṣọtẹ́lẹ̀ ìwé mímọ́ kankan tí ó wáyé nípa ìtumọ́ wòlìí fún rara rẹ̀ Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipá ìfẹ́ ènìyàn wá rí ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ̀ wá Àwọn Olúkọni Èké Àti Ìparun Wọn Ṣùgbọ́n àwọn wòlíì èké wà láàrin àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ni èké yóò ti wà láàrin yín Wọn yóò yọ́lẹ̀ mú ẹ̀kọ́ òdì àti ègbé tọ̀ yín wa, àní tí yóò sẹ́ Olúwa tí ó rà wọ́n padà, wọ́n ó sì mú ìparun ti o yára kánkán wá sorí ara wọn Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì-sí Nínù ìwà wòbìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀-òdì wọ̀nyìí yóò máa reẹ ẹ yín jẹ́ nípa ìtàn àsán Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé Nítorí pé bi Ọlọ́run kò bá dá àwọn ańgẹ́lì si nígbà tí wọn ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ti ó sọ wọ́n sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun tí ó sì fi wọ́n sínú ọ̀gbun òkùnkùn biribiri nínú ìfipamọ́ títí dé ìdájọ́ Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Nóà mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn Tí ó sọ àwọn ìlú Sódómù àti Gòmórà di eérú, nígbà tí ó fi ìparun pátapáta dá wọn lẹ́bí, tí ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run Tí ó sì yọ Lọ́tì olóòótọ́ ènìyàn, ẹni tí ìwà ẹ̀gbin àwọn ènìyàn láìlófin bà nínú jẹ́ Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdẹwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀sẹ̀ wọn Ṣùgbọ́n páàpáà àwọn tí ó ń tọ ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè, àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ańgẹ́lì bí wọ́n ti pọ̀ ní agbára àti ipá tó ò ní wọn kò dá wọ́n lẹ́jọ́ ẹ̀gàn níwájú Olúwa Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ohun tí kò yé wọn Wọ́n dàbí ẹranko tí a kò lè tù lójú, àwọn ẹ̀dá aláròse, tí a dá láti máa mú pa, bí ẹranko ni wọ́n yóò sí sègbé pẹ̀lú Wọn yóò gba ibi padà bí ibi tí wọ́n ti ṣe Òye ìgbafẹ́ tí wọ́n ní láti máa jẹ adùn ayé Wọ́n jẹ́ àbàwọ́n àti àbùkù, wọ́n ń jáyé nínú ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ń jẹ àṣè pẹ̀lú yín Ojú wọn kún fún panságà, wọn kò sì dẹ́kun ẹ̀sẹ̀ dídá wọ̀n ń tan àwọn tí kò dúró ṣinṣin wọ́n yege nínú iṣẹ́ wọ̀bìà, ẹni ègún ni wọ́n Wọ́n kọ ọ̀nà tí ó tọ́ sílẹ̀, wọ́n sì sáko lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀ná Bálámù ọmọ Béórì, ẹni tó fẹ́ràn èrè àìsòdodo Ṣùgbọ́n a bá a wí nítorí àṣìse rẹ̀, ẹranko tí ó kò le sọ̀rọ̀, ẹni tí ó fi ohùn ènìyàn sọ̀rọ̀ tí ó sì fi òpin sí ìsíwèrè wòlíì náà Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkuuku tí ẹ̀fúúfù ń gbá kiri àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìsìnà Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́ nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọgá ènìyàn Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olúgbála wá Jésù Kírísítì, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a buru jú ti ìṣáájú lọ Nítorí ìbá sàn fún wọn, kí wọ́n má mọ́ ọ̀nà òdodo, jù pé lẹ́yìn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tán, kí wọ́n yípadà kúrò nínú òfin mímọ́ tí a fi fún wọn Òwe òtítọ́ náà ṣẹ sí wọn lára Ajá tún padà sí èébì ara rẹ̀ àti ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀ mọ́ tún padà ń yíràá nínú ẹrọ̀fọ̀ Ọjọ́ Olúwa Olùfẹ́, èyí ni ìwé kejì tí mo ń kọ sí yín, nínú méjèèjì náà ni èmi ń ru èrò inú yín sókè nípa rírán yín létí Kí ẹ̀yín lè máa rántí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì mímọ́ sọ ṣáájú, àti òfin Olúwa àti Olùgbàlà wa láti ọ̀dọ̀ àwọn àpósítélì yín Kí ẹ kọ́ mọ èyí pé, nígbà ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹlẹ́gàn yóò dé pẹ̀lú ẹ̀gàn wọn Wọn ó máa rìn nípa ìfẹ́ ara wọn Wọn ó sì máa wí pé, Níbo ni ìlérí wíwà rẹ̀ gbé wà Láti ìgbà tí àwọn baba ti sùn, ohun gbogbo ń lọ bí wọ́n ti wà rí láti ìgbà ọjọ́ yìí wá Nítorí èyí ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe àìfẹ́ẹ́ mọ̀ pé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ọ̀run ti wà láti ìgbà àtijọ́ àti tí ilẹ̀ yọrí jáde nínú omi, tí ó sì dúró nínú omi Nípa èyí tí omi bo ayé tí ó wà nígbà náà tí ó sì ṣègbé Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run àti ayé, tí ó ń bẹ nísinsìnyìí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà ni ó ti tò jọ bí ìṣúra fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run Ṣùgbọ́n, olùfẹ́, ẹ má ṣe gbàgbé ohun kan yìí, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa bí ẹgbẹ̀rún ọdún ni ó rí, àti ẹgbẹ̀rún ọdún bí ọjọ́ kan Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa ń bọ̀wá bí olè ní òru nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́, ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ó wà nínú rẹ̀ yóò sì jóná lúúlúú Ǹjẹ́ bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti yọ́ bẹ́ẹ̀, irú ènìyàn wo ni ẹ̀yin ìbá jẹ́ nínú ìwà-mímọ́ gbogbo àti ìwà-bí-Ọlọ́run Kí ẹ máa reti kí ẹ sì máa múra gírí de dídé ọjọ́ Ọlọ́run, nítorí èyí tí àwọn ọ̀run yóò gbiná, tí wọn yóò di yíyọ́, tí àwọn ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́ Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, àwa ń retí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé títún nínú èyí tí òdodo ń gbé Nítorí náà, olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti ń retí irú nǹkan wọ̀nyí, ẹ múra gírí, kí a lè bá yín ní àlàáfíà ní àìlábàwọ́n, àti ní àìlábùkù lójú rẹ̀ Kí ẹ sì máa kà á sí pé, sùúrù Olúwa wa ìgbàlà ni bí Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú arákùnrin wa olùfẹ́, ti kọ̀wé sí yín gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a fi fún un Bí ó tí ń ṣọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú nínú ìwé rẹ̀ gbogbo nínú èyí ti ohun mìíràn ṣọ̀rọ̀ láti yé ni gbé wà, èyí ti àwọn òpè àti àwọn aláìdúró níbìkan ń lọ́, bí wọ́n ti ń lo ìwé-mímọ́ ìyókù, sí ìparun ara wọn Nítorí náà ẹ́yín olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti mọ nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀, ẹ máa kiyé sára, kí a má baà fi ìsìnà àwọn ènìyàn búburú fà yín lọ, kí ẹ sì ṣubú kúrò ní ìdúró-ṣinṣin yín Ṣùgbọ́n ẹ máa dàgbà nínú oore-ọ̀fẹ́ àti nínú ìmọ̀ Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kírísítì ẹni tí ògo wà fún nísinsìn yìí àti títí láé Àmín Lẹ́yìn ikú Ṣọ́ọ̀lù, Dáfídì ti ibi tí ó ti ṣẹ́gun àwọn ará Ámálékì bọ̀, ó sì dúró ní Síkílágì ní ọjọ́ méjì Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan dé láti ibi ibùdó Ṣọ́ọ̀lù, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya àti erùpẹ̀ ní orí rẹ̀ Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dáfídì, ó wólẹ̀ fún un láti bu ọlá fún un Dáfídì sì béèrè pé, Ibo ni ìwọ ti wá Èmi sá láti ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Dáfídì béèrè pé, Kí ni ó ṣẹlẹ̀  Sọ fún mi Ó wí pé, Àwọn ọkùnrin náà sá láti ojú ogun Ọ̀pọ̀ wọn ṣubú, wọ́n sì kú Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Jónátanì sì kú pẹ̀lú Nígbà náà, ní Dáfídì sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọkùnrin rẹ̀ Jónátanì ti kú Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, mo wà ní orí òkè Gílíbóà níbẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀ Nígbà tí ó wò yíká, tí ó rí mí, ó pè mi, mo sì wí pé, kí ni mo lè ṣe Ó bi mí wí pé, Ta ni ìwọ Mo dáhùn pé, Ará a Ámálékì, Nígbà náà ó wí fún mi pé, Dúró lórí ì mi kí o sì pa mí! Èmi wà nínú ìrora ikú, ṣùgbọ́n mo wà láàyè Nígbà náà, mo dúró lórí i rẹ̀, mo sì pa á nítorí mo mọ̀ wí pé, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣubú, kò le è yè mọ́ Mo sì mú adé tí ó wà lórí rẹ̀, idẹ tí ó wà ní apá a rẹ̀, mo sì kó wọn wá síbí fún Olúwa mi Nígbà náà ni, Dáfídì àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, di aṣọ wọn mú, wọ́n sì fà á ya Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì sunkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ Jónátanì àti fún àwọn ọmọ ogun Olúwa , àti fún àwọn ilé Ísírẹ́lì, nítorí wọ́n ti ṣubú nípa idà Dáfídì sọ fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, Níbo ni ó ti wá O dáhùn pé, Ọmọ àlejò ni mo jẹ́, ará Ámálékì Dáfídì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Kí ni ó dé tí ìwọ kò fi bẹ̀rù láti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti fi pa ẹni àmì òróró Olúwa Nígbà náà Dáfídì pe ọ̀kan nínú ọkùnrin, ó sì wí pé, Lọ, gbé e lulẹ̀! Nígbà náà ó gbé e lulẹ̀, ó sì kú Nítorí Dáfídì wí fún un pé, Ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò wà lórí ara rẹ, nítorí ẹnu ara rẹ ni o fi sọ pé Mo pa ẹni àmì òróró Olúwa   Dáfídì sì fi orin arò yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Ṣọ́ọ̀lù àti lórí Jónátanì ọmọ rẹ̀, Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Júdà ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun Ogo rẹ, Ísírẹ́lì ni a pa ní òkè gíga rẹ Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú! Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gátì, ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Áṣíkélónì, kí àwọn ọmọbìnrin Fílístínì má bá à yọ̀, kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má baà dunnú Ẹ̀yin òkè Gílíbóà, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò, tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá Nítorí ibẹ̀ ni aṣà alágbára ti ṣègbé, aṣà Ṣọ́ọ̀lù, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án Ọrun Jónátánì kì í padà bẹ́ẹ̀ ni idà Ṣọ́ọ̀lù kì í padà lásán, láì kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa, àti ẹran àwọn alágbára Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì— ní ọjọ́ ayé, wọ́n fẹ́ràn ara, wọn sì dùn, ní ikú, wọn kò sì yà ara wọ́n Wọ́n yára ju àṣá lọ, wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ísírẹ́lì, ẹ sunkún lórí Ṣọ́ọ̀lù, ẹni tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára wọ̀ yín, ẹni tí ó fí wúrà sí ara aṣọ yín Wò ó bí alágbára ti ṣubú ní ojú ogun! Jónátánì, ìwọ tí a pa ní òkè gíga Ọkàn mi gbọgbẹ́ fún ọ Jónátanì arákùnrin mi ìwọ ṣọ̀wọ́n fún mi Ìfẹ́ rẹ sí mi jẹ́ ìyanu, ó jẹ́ ìyanu ju ti obìnrin lọ Wò ó bí alágbára ti ṣubú! Ohun ìjà sì ti ṣègbé! A Dójúti Àwọn Ìránṣẹ́ Dáfídì Ní Ilé Ámónì Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, ọba àwọn ọmọ Ámónì sì kú, Hánúnì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀ Dáfídì sì wí pé, Èmi yóò ṣe ooré fún Hánúnì ọmọ Náhásì gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ sì ti ṣe oore fún mi Dáfídì sì ìránṣẹ́ láti tù ú nínú láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá, nítorí ti baba rẹ̀ Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì wá sí ilé àwọn ọmọ Ámónì Àwọn olórí àwọn ọmọ Ámónì sì wí fún Hánúnì Olúwa wọn pé, Ǹjẹ́ o rò pé Dáfídì ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn Kò ha ṣe pé Dáfídì rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́ Hánúnì sì mú àwọn ìránṣẹ Dáfídì ó fá apákan irungbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúró ní agbádá wọn, títí ó fí dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ Wọ́n sì sọ fún Dáfídì, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀ ọba sì wí pé, Ẹ dúró ní Jẹ́ríkò títí irungbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀ Àwọn ọmọ Ámónì sì ri pé, wọ́n di ẹni ìríra níwájú Dáfídì, àwọn ọmọ Ámónì sì ránṣẹ, wọ́n sì fi owó bẹ́ ogún àwọn ará Síríà ti Bẹtire-hóhù àti Síríà ti Sóbà, ẹgbaàwá ẹlẹ́sẹ̀ àti ti ọba Máákà, ẹgbẹ̀run ọkùnrin àti ti Isítóbù ẹgbàafà ọkùnrin lọ́wẹ̀ Dáfídì sì gbọ́, ó sì rán Jóábù, àti gbogbo ogún àwọn ọkùnrin alágbára Àwọn ọmọ Ámónì sì jáde, wọ́n sì tẹ́ ogún ní ẹnu odi ará Síríà ti Sóbà, àti ti Réhóbù, àti Ísítóbù, àti Máákà, wọ́n sì tẹ ogun ni pápá fún ara wọn Nígbà tí Jóábù sì ríi pé ogun náà dojú kọ òun níwájú àti lẹ́yìn, ó sì yàn nínú gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin ní Ísírẹ́lì, ó sì tẹ́ ogun kọjú sí àwọn ará Síríà Ó sì fi àwọn ènìyàn tí ó kù lé Ábíṣáì àbúrò rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè tẹ ogun kọjú sí àwọn ọmọ Ámónì Ó sì wí pé, Bí agbára àwọn ará Síríà bá pọ̀ ju èmi lọ, ìwọ yóò sì wá ràn mí lọ́wọ́ ṣùgbọ́n bí ọwọ́ àwọn ọmọ Ámónì bá sì pọ̀ jù ọ́ lọ, èmi ó sì wá ràn ọ́ lọ́wọ́ Mú ọkàn lè, jẹ́ kí a ṣe onígboyà nítorí àwọn ènìyàn wa, àti nítorí àwọn ìlú Ọlọ́run wa Olúwa yóò sì ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀ Jóábù àti àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì bá àwọn ará Síríà pàdé ìjà wọ́n sì sá níwájú rẹ̀ Nígbà tí àwọn ọmọ Ámónì sì ríi pé àwọn ará Síríà sá, àwọn pẹ̀lú sì sá níwájú Ábíṣáì, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ Jóábù sì padà kúrò lẹ́yìn àwọn ọmọ Ámónì, ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù Nígbà tí àwọn ará Síríà sì ríi pé Àwọn ṣubú níwájú Ísírẹ́lì wọ́n sì kó ara wọn jọ Hadadésérì sì ránṣẹ́, ó sì mú àwọn Síríà tí ó wà ní òkè odò jáde wá wọ́n sì wá sí Hélámì Sóbákì olórí ogun Hedareṣérì sì ṣe olórí wọn Nígbà tí a sọ fún Dáfídì, ó sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì kọjá Jọ́dánì, wọ́n sì wá sí Hélámì, Àwọn ará Síríà sì tẹ́ ogun kọjú sí Dáfídì, wọ́n sì bá a jà Àwọn ará Síríà sì sá níwájú Ísírẹ́lì, Dáfídì sì pa nínú àwọn ará Síríà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àwọn oníkẹ̀kẹ́, àti ọ̀kẹ́ méjì ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì kọlu Sóbákì olórí ogun wọn, ó sì kú níbẹ́ Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí ó wà lábẹ́ Hadadésérì sì ríi pé wọ́n di bíbì ṣubú níwájú Ísírẹ́lì, wọ́n sì bá Ísírẹ́lì làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n Àwọn ará Síríà sì bẹ̀rù lati máa ran àwọn ọmọ Ámónì lọ́wọ́ mọ́ Dáfídì Bá Bátísébà Ṣe àgbèrè Lẹ́yìn ìgbà tí ọdún yípo, ní àkókò ìgbà tí àwọn ọba náà ń jáde ogun, Dáfídì sì rán Jóábù, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àti gbogbo Ísírẹ́lì wọ́n sì pa àwọn ọmọ Ámónì, wọ́n sì dó ti Rábà Dáfídì sì jókòó ní Jérúsálẹ́mù Ó sì ṣe, ní ìgbà àṣálẹ́ kan, Dáfídì sì díde ní ibùsùn rẹ̀, ó sì ń rìn lórí òrùlé ilé ọba, láti orí òrùlé náà ni ó sì rí obìnrin kan tí ó ń wẹ̀ ara rẹ̀ obìnrin náà sì ṣe arẹwà lójú láti wò Dáfídì sì ránṣẹ́ ó sì béèrè obìnrin náà Ẹnìkan sì wí pé, Èyí ha kọ́ ni Báṣébà, ọmọbìnrin Élíámì, aya Úráyà ará Hítì Dáfídì sì rán àwọn ìránṣẹ́, ó sì mú un ó sì wọ inú ilé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a dàpọ̀ nígbà tí ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ tán, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀ Obìnrin náà sì lóyún, ó sì ránṣẹ́ ó sì sọ fún Dáfídì, ó sì wí pé, Èmi lóyún Dáfídì sì ránṣẹ́ sí Jóábù, pé Rán Ùráyà ará Hítì sí mi Jóábù sì rán Ùráyà sí Dáfídì Nígbà tí Ùráyà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Dáfídì sì bi í léèrè báwo ni Jóábù ti ṣe àti àlàáfíà àwọn ènìyàn náà, àti bí ogun náà ti ń ṣe Dáfídì sì wí fún Ùráyà pé, Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ, kí o sì wẹ ẹṣẹ̀ rẹ Ùráyà sì jáde kúrò ní ilé ọba, oúnjẹ láti ọ̀dọ̀ ọba wá sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Ṣùgbọ́n Ùráyà sun l'ẹ́nu ọ̀nà ilé ọba lọ́dọ̀ gbogbo ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ Nígbà tí wọ́n sì sọ fún Dáfídì pé, Ùráyà kò sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀, Dáfídì sì wí fún Ùráyà pé, Ṣebí ọ̀nà àjò ni ìwọ ti wá Èé ha ti ṣe tí ìwọ kò fi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ Ùráyà sì wí fún Dáfídì pé, Àpótí-ẹ̀rí, àti Ísírẹ́lì, àti Júdà jókòó nínú àgọ́ àti Jóábù olúwa mi, àti àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi wà ní ibùdó ní pápá èmi ó ha lọ sí ilé mi, láti jẹ ati lati mu, àti láti bá obìnrin mi sùn Bí ìwọ bá wà láàyè, àti bí ẹ̀mí rẹ́ si ti ń bẹ láàyè, èmi kì yóò ṣe nǹkan yìí Dáfídì sì wí fún Ùráyà pé, Ṣì dúró níhìn ín lónìí, lọ́la èmi ó sì jẹ́ kí ìwọ ó lọ Ùráyà sì dúró ní Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ náà, àti ijọ́ kejì Dáfídì sì pè é, ó sì jẹ, ó sì mú nítorí rẹ̀ ó sì mu kí ọtí pa á òun sì jáde ní alẹ́ lọ sí ibùsùn rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ́ lọ sí ilé rẹ̀ Ó sì ṣe ní òwúrọ̀, Dáfídì sì kọ̀wé sí Jóábù, ó fi rán Ùráyà Ó sì kọ sínú ìwé pé, Fi Ùráyà ṣíwájú ibi tí ogun gbé le, kí ẹ sì fà sẹ́yìn, kí wọn lè kọ lù ú, kí ó sì kú Ó sì ṣe nígbà tí Jóábù ṣe àkíyèsí ìlú náà, ó sì yan Úráyà sí ibi kàn ní ibi tí òun mọ̀ pé àwọn alágbára ọkùnrin ń bẹ níbẹ̀ Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì jáde wá, wọ́n sì bá Jóábù jà díẹ̀ sì ṣubú nínú àwọn ènìyàn náà nínú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, Ùráyà ará Hítì sì kú pẹ̀lú Jóábù sì ránṣẹ́ ó sì ro gbogbo nǹkan ogun náà fún Dáfídì Ó sì pàṣẹ fún ìránṣẹ́ náà pé, Nígbà tí iwọ bá sì parí àti máa ro gbogbo nǹkan ogun náà fún ọba Bí ó bá ṣe pé, ibinú ọba bá fàru, ti òun sì wí fún ọ pé, Èéṣe tí ẹ̀yin fí súnmọ́ ìlú náà láti bá wọn jà, ẹ̀yin kò mọ̀ pé wọn ó tafà láti orí odì wá Ta ni ó pa Ábímélékì ọmọ Jerubu-Bésétì Kì í ṣe obìnrin ni ó yí òkúta ọlọ lù ú láti orí odi wá, tí ó sì kú ní Tébésì Èé ha ti rí tí ẹ̀yín fi súnmọ́ odi náà Ìwọ yóò sì wí fún-un pé, Ùráyà ìránṣẹ́ rẹ ará Hítì kú pẹ̀lú   Ìránṣẹ́ náà sì lọ, ó sì wá, ó sì jẹ́ gbogbo iṣẹ́ tí Jóábù rán an fún Dáfídì Ìránṣẹ́ náà sì wí fún Dáfídì pé, Nítòótọ́ àwọn ọkùnrin náà lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde tọ̀ wá wá ní pápá, àwa sì tẹ̀lé wọn títí wọ́n fi dé ẹ̀yìn odi Àwọn tafàtafà sì ta sí ìránṣẹ́ rẹ láti orí odi wá, díẹ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ ọba sì kú, ìránṣẹ́ rẹ̀ Ùráyà ará Hítì sì kú pẹ̀lú Dáfídì sì wí fún ìránṣẹ́ náà pé, Báyìí ni ìwọ yóò wí fún Jóábù pé, Má ṣe jẹ́ kí nǹkan yìí burú ní ojú rẹ, nítorí pé idà a máa jẹ́ lọ́tún lósì, mú ìjà rẹ le sí ìlú náà, kí o sì bì í ṣubú Kí ìwọ sì mú un lọ́kàn le Nígbà tí aya Ùráyà sì gbọ́ pé Ùráyà ọkọ rẹ̀ kú, ó sì ṣọ̀fọ̀ nítorí ọkọ rẹ̀ Nígbà tí ìṣọ̀fọ̀ náà sì kọjá tan, Dáfídì sì ránṣẹ́, o sì mú un wá sí ilé rẹ̀, ó sì di aya rẹ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un, ṣùgbọ́n nǹkan náà tí Dáfídì ṣe burú níwájú Olúwa Nátanì Bá Dáfídì Wí Olúwa sì rán Nátanì sí Dáfídì òun sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, Ọkùnrin méjì ń bẹ ní ìlú kan ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ talákà Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà sì ní àgùntàn àti màlúù lọ́pọ̀lọpọ̀ Ṣùgbọ́n ọkùnrin talákà náà kò sì ní nǹkan bí kò ṣe àgùntàn kékeré kan èyí tí ó sì ń tọ́ ó sì dàgbà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ a máa jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀, a sí máa mu nínú ago rẹ̀, a sì máa dúbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀, ó sì dàbí ọmọbìnrin kan fún un Àlejò kan sì tọ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà wá, òun kò sì fẹ́ mú nínú àgùntàn rẹ̀, àti nínú màlúù rẹ̀ láti fi ṣe àlejò fún ẹni tí ó tọ̀ ọ́ wá o sì mú àgùntàn ọkùnrin talákà náà fi ṣe àlejò fún ọkùnrin tí ó tọ̀ ọ́ wá Ìbínú Dáfídì sì fàru gidigidi sí ọkùnrin náà ó sì wí fún Nátanì pé, Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkán yìí, kíkú ni yóò kú Òun yóò sì san àgùntàn náà padà ní mẹ́rinmẹ́rin, nítorí tí ó ṣe nǹkan yìí àti nítorí tí kò ní àánú Nátanì sì wí fún Dáfídì pé, Ìwọ ni ọkùnrin náà Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, Èmi fi ọ́ jọba lórí Ísírẹ́lì, èmi sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀lù Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Ísírẹ́lì àti ti Júdà fún ọ tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ ẹ̀ lọ Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gan ọ̀rọ̀ Olúwa , tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Ùráyà ará Hítì, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ámónì pa á Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúró ní ilé rẹ títí láé nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Úráyà ará Hítì láti ṣe aya rẹ Bàyìí ni Olúwa wí, Kíyèsí i, Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrun yìí Àti pé ìwọ ṣe é ní ìkọ̀kọ̀ Ṣùgbọ́n èmi ó ṣe nǹkan yìí níwájú gbogbo Ísírẹ́lì, àti níwájú òòrun   Dáfídì sì wí fún Nátanì pé, Èmi ṣẹ̀ sí Olúwa ! Nátanì sì wí fún Dáfídì pé, Olúwa pẹ̀lú sì ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò ìwọ kì yóò kú Ṣùgbọ́n nítorí nípa ìwà yìí, ìwọ fi àyè sílẹ̀ fún àwọn ọ̀ta Olúwa láti sọ ọ̀rọ̀ òdì, ọmọ náà tí a ó bí fún ọ, kíkú ní yóò kú Nátanì sì lọ sí ilé rẹ̀ Olúwa sì fi àrùn kọlu ọmọ náà tí obìnrin Úráyà bí fún Dáfídì, ó sì ṣe àìsàn púpọ̀ Dáfídì sì bẹ Ọlọ́run nítorí ọmọ náà, Dáfídì sì gbààwẹ̀, ó sì wọ inú ilé lọ, ó sì dúbúlẹ̀ lorí ilé ni orú náà Àwọn àgbà ilé rẹ̀ sì dìde tọ̀ ọ́ lọ, láti gbé e dìde lórí ilé ó sì kọ̀, kò sì bá wọn jẹun Ní ijọ́ keje, ọmọ náà sì kú Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú nítorí tí wọ́n wí pé, Kíyèsí i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní ìṣẹ́ tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú Nígbà tí Dáfídì sì rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, Dáfídì sì kìyésí i, pé ọmọ náà kú Dáfídì sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Ọmọ náà kú bí Wọ́n sì dá a lóhùn pé, Ó kú Dáfídì sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé Olúwa lọ, ó sì wólẹ̀ sin ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì bèèrè, wọ́n sì gbé òunjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, Kí lèyí tí ìwọ ṣe yìí Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láàyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sunkún ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun Ó sì wí pé, Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sunkún nítorí tí Èmi wí pé, Ta ni ó mọ̀ bí Ọlọ́run ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti kú, nítorí kín ni èmi ó ṣe máa gbààwẹ̀ Èmi ha tún lè mú-un padà bí Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ, òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá Dáfídì sì ṣìpẹ̀ fún Bátíṣébà aya rẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a dàpọ̀ òun sì bí ọmọkùnrin kan, Dáfídì sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Sólómónì Olúwa sì fẹ́ ẹ Ó sì rán Nátanì wòlíì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jédídíáyà, nítorí Olúwa Jóábù sì bá Rábà ti àwọn ọmọ Ámónì jagun, ó sì gba ìlú ọba wọn Jóábù sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dáfídì, ó sì wí pé, Èmi ti bá Rábà jà, èmi sì ti gba àwọn ìlú olomi Ǹjẹ́ nítorí náà kó àwọn ènìyàn ìyókù jọ, kí o sì dó ti ìlú náà, kí o sì gbà á, kí èmi má báà gba ìlú náà kí a má baà pè é ní orúkọ mi Dáfídì sì kó gbogbo ènìyàn náà jọ, sí Rábà, ó sì bá a jà, ó sì gbà á Òun sì gba adé ọba wọn kúrò lórí rẹ̀, ìwúwo rẹ̀ sì jẹ́ talẹ́ńtì wúrà kan, ó sì ní òkúta oníyebíye lára rẹ̀ a sì fi dé Dáfídì lórí Òun sì kó ìkógun ìlú náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ó sì kó àwọn ènìyàn náà tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ ayùn, àti sí iṣẹ́ nǹkan ìtùlẹ̀ tí a fi irin ṣe, àti sí iṣẹ́ àáké irin, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ bíríkì ṣíṣe bẹ́ ẹ̀ náà ni òun sì ṣe sí gbogbo ìlú àwọn ọmọ Ámónì Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì padà sí Jérúsálẹ́mù Ámúnónì Bá Arábìnrin Rẹ̀ Dàpọ̀ Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Ábúsálómù ọmọ Dáfídì ní àbúrò obìnrin kan tí ó ṣe arẹwà, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Támárì Ámúnónì ọmọ Dáfídì sì fẹ́ràn rẹ̀ Ámúnónì sì banújẹ́ títí ó fi ṣe àìsàn nítorí Támárì àbúrò rẹ̀ obìnrin nítorí pé wúndíá ni ó sì ṣe ohun tí ó ṣòro lójú Ámúnónì láti bá a dàpọ̀ Ṣùgbọ́n Ámúnónì ní ọ̀rẹ́ kan, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Jónádábù, ọmọ Ṣíméà ẹ̀gbọ́n Dáfídì Jónádábù sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn gidigidi Ó sì wí fún un pé, Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójojúmọ́ báyìí Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi Ámúnónì sì wí fún un pé, Èmi fẹ́ Támárì àbúrò Ábúsálómù arákùnrin mi Jónádábù sì wí fún un pé, Dùbúlẹ̀ ní ibùsùn rẹ kí ìwọ sì díbọ́n pé, ìwọ kò sàn baba rẹ yóò sì wá wò ó, ìwọ ó sì wá fún un pé, Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Támárì àbúrò mi wá kí ó sì fún mi ní oúnjẹ́ kí ó sì ṣe oúnjẹ náà níwájú mi kí èmi ó rí i, èmi ó sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀   Ámúnónì sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn ọba sì wá wò ó, Ámúnónì sì wí fún ọba pé, Jọ́wọ́, jẹ́ kí Támárì àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀ Dáfídì sì ránṣẹ́ sí Támárì ní ilé pé, Lọ sí ilé Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ, kí ó sì ṣe òunjẹ́ fún un Támárì sì lọ sí ilé Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdúbúlẹ̀ Támárì sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà Òun sì mú àwo náà, ó sì dà á sínú àwo mìíràn níwájú rẹ̀ ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ Ámúnónì sì wí pé, Jẹ́ kí gbogbo ọkùnrin jáde kúrò lọ́dọ̀ mi! Wọ́n sì jáde olúkúlùkù ọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ Ámúnónì sì wí fún Támárì pé, Mú oúnjẹ náà wá sí yàrá, èmi ó sì jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ Támárì sì mú àkàrà tí ó ṣe, ó sì mú un tọ Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní yàrá Nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti fi oúnjẹ fún un, òun sì dì í mú, ó sì wí fún un pé, Wá dùbúlẹ̀ tì mí, àbúrò mi Òun sì dá a lóhùn wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀gbọ́n mi, má ṣe tẹ́ mi nítorí pé kò tọ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Ísírẹ́lì, ìwọ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí Àti èmi, níbo ni èmi ó gbé ìtìjú mi wọ̀ Ìwọ ó sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ní Ísírẹ́lì Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́, sọ fún ọba nítorí pé òun kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́ ohùn rẹ̀ ó sì fi agbára mú un, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì bá a dàpọ̀ Ámúnónì sì kóríra rẹ̀ gidigidi, ìríra náà sì wá ju ìfẹ́ tí òun ti ní sí i rí lọ Ámúnónì sì wí fún un pé, Dìde, kí o sì máa lọ! Òun sì wí fún un pé, Kó ha ní ìdí bí! Lílé tí ìwọ ń lé mi yìí burú ju èyí tí ìwọ ti ṣe sí mi lọ Ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀ Òun sì pe ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, Jọ̀wọ́, ti obìnrin yìí sóde fún mi, kí o sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan làra rẹ̀ nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúndíá máa ń wọ̀ Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn Támárì sì bu èérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ aláràbarà tí ń bẹ lára rẹ̀ ya, ó sì ká ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń kígbe bí ó ti ń lọ Ábúsálómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ Támárì sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Ábúsálómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Ṣùgbọ́n nígbà tí Dáfídì ọba gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi Ábúsálómù kò sì bá Ámíúnónì sọ nǹkan rere, tàbí búburú nítorí pé Ábúsálómù kóríra Ámúnónì nítorí èyí tí ó ṣe, àní tí ó fi agbára mú Támárì àbúrò rẹ̀ Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Ábúsálómù sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baalihásórì, èyí tí ó gbé Éfúráímù Ábúsálómù sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba Ábúsálómù sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ Ọba sì wí fún Ábúsálómù pé, Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má báà mú ọ náwó púpọ̀ Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un Ábúsálómù sì wí pé, Bí kò bá le rí bẹ́ ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Ámúnónì ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ Ọba sì wí pé, Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ Ábúsálómù sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Ámúnónì àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ Ábúsálómù sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Kí ẹ̀yin máa kíyèsí àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Ámúnónì dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, Kọlu Ámúnónì, kí ẹ sì pa á Ẹ má bẹ̀rù Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ Àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù sì ṣe sí Ámúnónì gẹ́gẹ́ bí Ábúsálómù ti páṣẹ Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlukú gun ìbaka rẹ̀, wọ́n sì sá Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìhìn sì dé ọ̀dọ̀ Dáfídì pé, Ábúsálómù pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya Jónádábù ọmọ Ṣíméà arakùnrin Dáfídì sì dáhùn ó sì wí pé, Kí Olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdé-kùnrin àwọn ọmọ ọba nítorí pé Ámúnónì nìkan ṣoṣo ni ó kú nítorí láti ẹnu Ábúsálómù wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Támárì àbúrò rẹ̀ Ǹjẹ́ kí Olúwa mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú nítorí Ámúnónì nìkan ṣoṣo ni ó kú Ábúsálómù sì sá Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si ríi pé, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ̀nà lẹ́yin rẹ̀ láti ìhà òkè wá Jónádábù sì wí fún ọba pé, Wò ó, àwọn ọmọ ọba ń bọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí Nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, sì wò ó àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n sì gbé ohùn wọn sòkè, wọ́n sì sunkún ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún ńláńlá Ábúsálómù sì sá, ó sì tọ Támáì lọ, ọmọ Ámíhúdù, ọba Gésúrì Dáfídì sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lojojúmọ́ Ábúsálómù sì sá, ó sì lọ sí Géṣúrì ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta Ọkàn Dáfídì ọba sì fà gidigidi sí Ábúsálómù nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Ámúnónì ó sáà ti kú Obìnrin Ará Tékóà Jóábù ọmọ Sérúíà sì kíyèsí i, pé ọkàn ọba sì fà sí Ábúsálómù Jóábù sì ránṣẹ́ sí Tekóà, ó sì mú ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti ibẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, Èmi bẹ̀ ọ́, ṣe bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ, kí o sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sára, kí o má sì ṣe fi òróró pa ara, kí o sì dàbí obìnrin ti ó ti ń ṣọ̀fọ̀ fún òkú lọ́jọ́ púpọ̀ Kí o sì tọ ọba wá, kí o sọ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí Jóábù sì fi ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu Nígbà tí obìnrin àrá Tékóà sì ń fẹ́ sọ̀rọ̀ fún ọba, ó wólẹ, ó dojúbolẹ̀, o sí bu ọlá fún un, o sì wí pé, Ọba, gbà mi Ọba sì bi í léèrè pé, Kin ni o ṣe ọ́ Òun sì dáhùn wí pé, Nítòótọ́ opó ni èmi ń ṣe, ọkọ mi sì kú Ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ sì ti ní ọmọkùnrin méjì, àwọn méjèèjì sì jọ jà lóko, kò sì si ẹni tí yóò là wọ́n, èkínní sì lu èkejì, ó sì pa á Sì wò ó, gbogbo ìdílé dìde sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, wọ́n sì wí pé, Fi ẹni tí ó pa arákùnrin rẹ fún wa, àwa ó sì pa á ní ipò ẹ̀mi arákùnrin rẹ̀ tí ó pa, àwa ó sì pa àrólé náà run pẹ̀lú wọn ó sì pa iná mi tí ó kù, wọn kì yóò sì fi orúkọ tàbí ẹni tí ó kú silẹ̀ fún ọkọ mi ní ayé Ọba sì wí fún obìnrin náà pé, Lọ sí ilé rẹ̀, èmi ó sì kìlọ̀ nítorí rẹ Obìnrin ará Tékóà náà sì wí fún ọba pé, Olúwa mi, ọba, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ náà wà lórí mi, àti lorí idilé baba mí kí ọba àti ìtẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ aláìlẹ́bi Ọba sì wí pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ sí ọ, mú Olúwa rẹ̀ tọ̀ mí wá, òun kì yóò sì tọ́ ọ mọ́ Ó sì wí pé, Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí ọba ó rántí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má ṣe ní ipá láti ṣe iparun, kí wọn o má bá a pa ọmọ mi! Òun sì wí pé, Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè ọ̀kan nínú irun orí ọmọ rẹ ki yóò bọ sílẹ̀ Obìnrin náà sì wí pé, Èmí bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ sọ̀rọ̀ kán fún Olúwa mi ọba Òun si wí pé, Má a wí Obìnrin náà sì wí pé, Nítorí kínni ìwọ sì ṣe ro irú nǹkan yìí sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run Nítorí pé ní sísọ nǹkan yìí ọba ní ẹ̀bi, nítorí pé ọba kò mú ìsáǹsá rẹ̀ bọ̀ wá ilé Nítorí pé àwa ó sáà kú, a ó sì dàbí omi tí a tú sílẹ̀ tí a kò sì lè ṣàjọ mọ́ nítorí bí Ọlọ́run kò ti gbà ẹ̀mí rẹ̀, ó sì ti ṣe ọ̀nà kí a má báa lé ìsáǹsá rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ Ǹjẹ́ nítorí náà ni èmi sì ṣe wá sọ nǹkan yìí fún Olúwa mi ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ti dẹ́rùbà mí ìránṣẹ́bìnrin rẹ sì wí pé, Ǹjẹ́ èmi ó sọ fún ọba ó lè rí bẹ́ẹ̀ pé ọba yóò ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún un Nítorí pé ọba ò gbọ́, láti gbà ìránṣẹ́bìnrin rẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin náà tí ó ń fẹ́ gé èmi àti ọmọ mi pẹ̀lú kúrò nínú ilẹ̀ ìní Ọlọ́run Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì wí pé, Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ọba Olúwa mi yóò sì jásí ìtùnú nítorí bí ańgẹ́lì Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni Olúwa mi ọba láti mọ rere àti búburú Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ   Ọba sì dàhùn, ó sì wí fún obìnrin náà pé, Má ṣe fi nǹkan tí èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ pamọ́ fún mi, èmi bẹ̀ ọ́ Obìnrin náà wí pé, Jẹ́ kí Olúwa mi ọba má a wí Ọba sì wí pé, Ọwọ́ Jóábù kò ha wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo èyí Obìnrin náà sì dáhùn ó sì wí pé, Bí ẹ̀mí rẹ ti ń bẹ láàyè, Olúwa mi ọba, kò sí ìyípadà sí ọwọ́ ọ̀tún, tàbí sí ọwọ́ òsì nínú gbogbo èyí tí Olúwa mi ọba ti wí nítorí pé Jóábù ìránṣẹ́ rẹ, òun ni ó rán mi, òun ni ó sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ lẹ́nu Láti mú irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá ni Jóábù ìránṣẹ́ rẹ ṣe ṣe nǹkan yìí Olúwa mi sì gbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n ańgẹ́lì Ọlọ́run, láti mọ gbogbo nǹkan tí ń bẹ̀ ní ayé Ọba sì wí fún Jóábù pé, Wò ó, èmi ó ṣe nǹkan yìí nítorí náà lọ, kí o sì mú ọmọdékùnrin náà Ábúsálómù padà wá Jóábù sì wólẹ̀ ó dojú rẹ̀ bolẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì súre fún ọba Jóábù sì wí pé, Lónìí ni ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé, èmi rí oore-ọ̀fẹ́ gbà lójú rẹ, Olúwa mi, ọba, nítorí pé ọba ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ Jóábù sì dìde, ó sì lọ sí Géṣúrì, ó sì mú Ábúsálómù wá sí Jérúsálẹ́mù Ọba sì wí pé, Jẹ́ kí ó yípadà lọ sí ilé rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó rí ojú mi Ábúsálómù sì yípadà sí ilé rẹ̀, kò sì rí ojú ọba Kó sì sí arẹ́wà kan ní gbogbo Ísírẹ́lì tí à bá yìn bí Ábúsálómù láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ kò sí àbùkù kan lára rẹ̀ Nígbà tí ó bá sì rẹ́ irun orí rẹ̀ òun sì wọn irun orí rẹ̀, ó sì jásí igba ṣẹ́kẹ́lì nínú òṣùwọ̀n ọba A sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún Ábúsálómù àti ọmọbìnrin kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Támárì òun sì jẹ́ obìnrin tí ó lẹ́wà lójú Ábúsálómù sì gbé ni ọdún méjì ní Jérúsálẹ́mù kò sì rí ojú ọba Ábúsálómù sì ránṣẹ́ sí Jóábù, láti rán an sí ọba ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì ránṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì òun kò sì fẹ́ wá Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Wò ó, oko Jóábù gbé ti èmi, ó sì ní ọkà níbẹ̀ ẹ lọ kí ẹ sì tinábọ̀ ọ́ Àwọn ìrànṣẹ́ Ábúsálómù sì tinábọ oko náà Jóábù sì dìde, ó sì tọ Ábúsálómù wá ní ilé, ó sì wí fún un pé, Èéṣe tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi tinábọ oko mi Ábúsálómù sì dá Jóábù lóhùn pé, Wò ó, èmi ránṣẹ́ sí ọ, wí pé, Wá níhìn-ín yìí, èmi ó sì rán ọ lọ sọ́dọ̀ ọba, láti béèrè pé, Kí ni èmi ti Géṣúrì wá si Ìbá sàn fún mí bí ó ṣe pé èmi wà lọ́hùn-ún ṣíbẹ̀!  Ǹjẹ́ nísinsin yìí jẹ́ kí èmi lọ síwájú ọba bí ó bá sì ṣe ẹ̀bi ń bẹ nínú mi, kí ó pa mí Jóábù sì tọ ọba wá, ó sì rò fún un ó sì ránṣẹ́ pe Ábúsálómù, òun sì wá sọ́dọ̀ ọba, ó tẹríba fún un, ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀ níwájú ọba, ọba sì fi ẹnu ko Ábúsálómù lẹ́nu Ábúsálómù Dìtẹ̀ Sí Dáfídì Baba Rẹ̀ Lẹ́yin èyí náà, Ábúsálómù sì pèṣè kẹ̀kẹ́ àti ẹsin fún ara rẹ̀, àti àádọ́ta ọmọkùnrin tí yóò máa sáré níwájú rẹ̀ Ábúsálómù sì dìde ní kùtùkùtù, ó sì dúró ní apákan ọ̀nà ẹnu ibodé bí ẹnìkan bá ní ẹjọ́ tí ó ń fẹ́ mú tọ ọba wá fún ìdájọ́, a sì pè é sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì bi í pé, Ará ìlú wo ni ìwọ Òun a sì dáhùn pé, Ìránṣẹ́ rẹ ti inú ọ̀kan nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì wá Ábúsálómù yóò sì wí fún un pé, Wò ó, ọ̀ràn rẹ sá dára, ó sì tọ́ ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ọba fi àṣẹ fún láti gbọ́ ọ̀ràn rẹ Ábúsálómù a sì wí pé, À bá jẹ́ fi mi ṣe onídájọ́ ní ilẹ̀ yìí! Kí olúkúlùkù ẹni tí ó ní ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn kan báà lè máa tọ̀ mí wá, èmi ìbá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún un Bẹ́ẹ̀ ni bí ẹnìkan bá sì súnmọ́ ọn láti tẹ́ribá fún un, òun a sì nawọ́ rẹ̀, a sì dì í mú, a sì fí ẹnu kò ó lẹ́nú Irú ìwà bàyìí ni Ábúsálómù sì fi fa ọkàn àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sọ́dọ̀ rẹ̀ Ó sì ṣe lẹ́yìn ogójì ọdún, Ábúsálómù sì wí fún ọba pé, Èmi bẹ́ ọ́, jẹ́ kí èmi ó lọ, kí èmi sì san ìlérí mi tí èmi ti ṣe fún Olúwa , ní Hébírónì Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan nígbà tí èmi ń bẹ ní Géṣúrì ní Síríà pé, Bí Olúwa bá mú mi padà wá sí Jérúsálẹ́mù, nítòótọ́, èmi ó sì sin Olúwa   Ọba sì wí fún un pé, Má a lọ ní àlàáfíà Ó sì dìde, ó sì lọ sí Hébúrónì Ṣùgbọ́n Ábúsálómù rán àmì sáàrin gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì pé, Nígbà tí ẹ̀yin bá gbọ́ ìró ìpè, kí ẹ̀yin sì wí pé, Ábúsálómù jọba ní Hébúrónì   Igba ọkùnrin sì bá Ábúsálómù ti Jérúsálẹ́mù jáde, nínú àwọn tí a ti pè wọ́n sì lọ nínú àìmọ̀kan wọn, wọn kò sì mọ nǹkankan Ábúsálómù sì ránṣẹ́ pe Áhítófélì ará Gílónì, ìgbìmọ̀ Dáfídì, láti ìlú rẹ̀ wá, àní láti Gílónì, nígbà tí ó ń rú ẹbọ Ìdìmọ̀lù náà sì le àwọn ènìyàn sì ń pọ̀ sọ́dọ̀ Ábúsálómù Ẹnìkan sì wá rò fún Dáfídì pé, Ọkàn àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ṣí sí Ábúsálómù Dáfídì sì wí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wá lọ́dọ̀ rẹ̀ ni Jérúsálẹ́mù pé, Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a sá lọ, nítorí pé kò sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ Ábúsálómù ẹ yára, kí a lọ kúrò, kí òun má báà yára lé wa bá, kí ó má sì mú ibi bá wa, kí ó má sì fi ojú idà pa ìlú run Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì wí fún ọba pé, Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa wa ọba ń fẹ́, wò ó, àwa ìránṣẹ rẹ̀ ti murá Ọba sì jáde, gbogbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀lé e Ọba sì fì mẹ́wàá nínú àwọn obìnrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa sọ́ ilé Ọba sì jáde, gbogbo ènìyàn sì tẹ̀lé e, wọ́n sì dúró ní ibìkan tí ó jìnnà Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì kọjá sí ìwájú rẹ̀, àti gbogbo àwọn Kérétì, àti gbogbo àwọn Pélétì, àti gbogbo àwọn ará Gítì, ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Gátì wá, sì kọjá níwájú ọba Ọba sì wí fún Ítaì, ará Gítì pé, Èéṣe tí ìwọ fi ń bá wa lọ pẹ̀lú, padà, kí o sì ba ọba jókòó nítorí pé aléjò ni ìwọ, ìwọ sì ti fi ìlú rẹ sílẹ̀ Lánàá yìí ni ìwọ dé, èmi ó ha sì mú kí ìwọ máa bá wá lọ kákiri lónìí bí Èmi ń lọ sí ibikíbi tí mo bá rí padà, kí o sì mú àwọn arakùnrin rẹ padà, kí àánú àti òtítọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ Ítaì sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, Bí Olúwa tí ń bẹ láàyè, àti bí Olúwa mi ọba ti ń bẹ láàyè, nítòótọ́ níbikíbi tí Olúwa mi ọba bá gbé wà, ìbáà ṣe nínú ikú, tàbí nínú ìyè, níbẹ̀ pẹ̀lú ni ìránṣẹ́ rẹ yóò gbé wà Dáfídì sì wí fún Ítaì pé, Lọ kí o sì rékọjá! Ítaì ará Gítì náà sì rékọjá, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọ kékèké tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ Gbogbo ìlú náà sì fi ohùn rara sunkún, gbogbo ènìyàn sì rékọjá ọba sì rékọjá odò Kídírónì, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì rékọjá, sí ìhà ọ̀nà ijù Sì wò ó, Sádókù pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ń ru àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà sọ̀kalẹ̀ Ábíátarì sí gòkè, títí gbogbo àwọn ènìyàn sì fi dẹ́kun àti máa kọjá láti ìlú wá Ọba sì wí fún Sádókù pé, Sì tún gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà padà sí ìlú bí èmi bá rí ojú rere gbà lọ́dọ̀ Olúwa , yóò sì tún mú mi padà wá, yóò sì fi àpótí-ẹ̀rí náà hàn mí àti ibùgbé rẹ̀ Ṣùgbọ́n bí òun bá sì wí pé, Èmi kò ní inú dídùn sí ọ, wò ó, èmi nì yìí, jẹ́ kí òun ó ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti tọ́ ní ojú rẹ̀ Ọba sì wí fún Sádókù àlùfáà pé, Aríran ha kọ́ ni ọ́ Padà sí ìlú ní àlàáfíà, àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì pẹ̀lú rẹ, Áhímásì ọmọ rẹ, àti Jónátanì ọmọ Ábíátárì Wò ó, èmi ó dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà, títí ọ̀rọ̀ ó fi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá láti sọ fún mi Sádókù àti Ábíátarì sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run padà sí Jérúsálẹ́mù wọ́n sì gbé ibẹ̀ Dáfídì sì ń gòkè lọ ní òkè igi ólífì, o sì ń sunkun bí ó ti ń gòkè lọ, ó sì bo orí rẹ̀, ó ń lọ láìní bàtà ní ẹṣẹ̀ gbogbo ènìyàn tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀, olúkúlùkù ọkùnrin sì bo orí rẹ̀, wọ́n sì ń gòkè lọ, wọ́n ń sunkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ Ẹnìkan sì sọ fún Dáfídì pé, Áhítófélì wà nínú àwọn asọ̀tẹ̀ pẹ̀lù Ábúsálómù Dáfídì sì wí pé, Olúwa , èmi bẹ̀ ọ́, sọ ìmọ̀ Áhítófélì di asán Ó sì ṣe, Dáfídì dé orí òkè, níbi tí ó gbé wólẹ̀ sin Ọlọ́run, sì wò ó, Húsáì ará Áríkà sì wá láti pàdé rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ yíya, àti erùpẹ̀, lórí rẹ̀ Dáfídì sì wí fún un pé, Bí ìwọ bá bá mi kọjá, ìwọ ó sì jẹ́ ìdíwọ́ fún mi Bí ìwọ bá sì padà sí ìlú, tí o sì wí fún Ábúsálómù pé, Èmi ó ṣe ìránṣẹ́ rẹ ọba, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ṣe ìránṣẹ́ baba rẹ nígbà àtíjọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sì jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nísínsinyìí, kí ìwọ sì bá ìmọ̀ Áhítófélì jẹ́ Ṣé Sádókù àti Ábíátarì àwọn àlùfáà wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ Yóò sì ṣe, ohunkóhùn tí ìwọ bá gbọ́ láti ilé ọba wá, ìwọ ó sì sọ fún Sádókù àti Ábíátarì àwọn àlùfáà Wò ó, àwọn ọmọ wọn méjèèjì sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn, Áhímásì ọmọ Sádókù, àti Jónátánì ọmọ Ábíátárì láti ọwọ́ wọn ni ẹ̀yín ó sì rán ohùnkóhun tí ẹ̀yín bá gbọ́ sí mi Húsáì ọ̀rẹ́ Dáfídì sì wá sí ìlú, Ábúsálómù sì wá sí Jérúsálẹ́mù Ṣíbà Ìránṣẹ́ Mefibóṣétì Nígbà tí Dáfídì sì fi díẹ̀ kọjá orí òkè náà, sì wò ó, Ṣíbà ìránṣẹ́ Mefíbóṣétì sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, òun àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí a ti dì ní gàárì, àti igba ìṣù àkàrà lórí wọn, àti ọgọ́rùn-ún ṣírì àjàrà gbígbẹ, àti ọgọ́rùn ún èṣo ẹ̀rún, àti ìgò ọtí-wáìnì kan Ọba sì wí fún Ṣíbà pé, Kí ni wọ̀nyí Ṣíbà sì wí pé, Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ̀nyí ni fún àwọn ará ilé ọba láti máa gùn àti àkàrà yìí, àti èso ẹ̀rún yìí ni fún àwọn ọdọmọdékùnrin láti jẹ àti ọtí-wáìnì yìí ni fún àwọn aláàárẹ̀ ní ijù láti mu Ọba sì wí pé, Ọmọ olúwa rẹ dà Ṣíbà sì wí fún ọba pé, Wò ó, ó jókòó ní Jérúsálẹ́mù nítorí tí ó wí pé, Lónìí ni ìdílé Ísírẹ́lì yóò mú ìjọba baba mi padà wá fún mi   Ọba sì wí fún Síbà pé, Wò ó, gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Mefíbóṣétì jẹ́ tìrẹ Ṣíbà sì wí pé, Mo túúbá, jẹ́ kí n rí ore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ, Olúwa mi ọba Dáfídì ọba sì dé Bahúrímù, sì wò ó, Ọkùnrin kan ti ibẹ̀ jáde wá, láti ìdílé Ṣọ́ọ̀lù wá, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣíméhì, ọmọ Gérà ó sì ń bú èébú bí o tí ń bọ̀ Ó sì sọ òkúta sí Dáfídì, àti sí gbogbo àwọn ènìyàn, gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin sì wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti lọ́wọ́ òsì rẹ̀ Báyìí ni Ṣímé sì wí nígbà tí ó ń yọ èébú, Jáde, ìwọ ọkùnrin ẹ̀jẹ̀, ìwọ ọkùnrin Bélíálì Olúwa mú gbogbo ẹ̀jẹ̀ ìdílé Ṣọ́ọ̀lù padà wá sí orí rẹ, ní ipò ẹni tí ìwọ jọba Olúwa ti fi ijọba náà lé Ábúsálómù ọmọ rẹ lọ́wọ́ sì wò ó, ìwà búburú rẹ ni ó mú èyí wá bá ọ, nítorí pé ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ Ábíṣáì ọmọ Serúià sì wí fún ọba pé, Èéṣe tí òkú ajá yìí fi ń bú Olúwa mi ọba Jẹ́ kí èmi kọjá, èmi bẹ̀ ọ́, kí èmi sì bẹ́ ẹ́ lórí Ọba sì wí pé, Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yín ọmọ́ Séríià Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí Olúwa ti wí fún un pé Bú Dáfídì! Ta ni yóò sì wí pé, kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀   Dáfídì sì wí fún Ábíṣáì, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Bẹ́ńjámínì yìí yóò sì ṣe Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú nítorí pé Olúwa ni ó sọ fún un Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ̀njú mi, Olúwa yóò sì fi ire san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣíméhì sì ń rìn lẹ́bá òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀ Ọba, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì dé Jódánì, ó sì rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì sinmi níbẹ̀ Ábúsálómù àti gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wá sí Jérúsálẹ́mù, Áhítófélì sì wà pẹ̀lú rẹ̀ Ó sì ṣe, nígbà tí Húṣáì ará Áríkì, ọ̀rẹ́ Dáfídì tọ Ábúsálómù wá, Húṣáì sì wí fún Ábúsálómù pé, Kí ọba ó pẹ́! Kí ọba ó pẹ́ Ábúsálómù sì wí fún Húṣáì pé, Oore rẹ sí ọ̀rẹ́ rẹ ni èyí Èéṣe tí ìwọ kò bá ọ̀rẹ́ rẹ lọ Húṣáì sì wí fún Ábúsálómù pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́ nítorí ẹni tí Olúwa , àti gbogbo àwọn ènìyàn yìí, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì bá yàn, tirẹ̀ lèmi ó jẹ́, òun lèmi ó sì bá jókòó Àti pé, ta ni èmi ó sì sìn Kò ha yẹ kí èmi ó máa sìn níwájú ọmọ rẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń sìn rí níwájú baba rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sìn níwájú rẹ Ábúsálómù sì wí fún Áhítófélì pé, Ẹ bá ará yín gbímọ ohun tí àwa ó ṣe Áhítófélì sì wí fún Ábúsálómù pé, Wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ lọ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì gbọ́ pé, ìwọ di ẹni-ìríra sí baba rẹ, ọwọ́ gbogbo àwọn tí ó wà lọdọ rẹ yóò sì le Wọ́n sì tẹ́ àgọ́ kan fún Ábúsálómù ní òrùlé Ábúsálómù sì wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ̀ lójú gbogbo Ísírẹ́lì Ìmọ̀ Áhítófélì tí ó máa ń gbà ni ìgbà náà, ó dàbí ẹni pé ènìyàn béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ìmọ̀ Áhítófélì fún Dáfídì àti fún Ábúsálómù sì rí Áhítófélì Gbìmọ̀ Pé Kí a Lépa Dáfídì Áhítófélì sì wí fún Ábúsálómù pé, Èmi ó yan ẹgbàáfà ọkùnrin èmi ó sì dìde, èmi ó sì lépa Dáfídì lóru yìí Èmi ó sì yọ sí i nígbà tí àárẹ̀ bá mú un tí ọwọ́ rẹ̀ sì ṣe aláìle, èmi ó sì dá a ní ìjì gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ yóò sì sá, èmi ó sì kọlu ọba níkan ṣoṣo Èmi ó sì mú gbogbo àwọn ènìyàn padà sọ́dọ̀ rẹ bi ìgbà tí ìyàwó bá padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀ Ọkàn ẹnìkan ṣoṣo tí ìwọ ń wá yìí ni ó túmọ̀ sí ìpadàbọ̀ gbogbo wọn gbogbo àwọn ènìyàn yóò sì wà ní àlàáfíà Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú Ábúsálómù, àti lójú gbogbo àwọn àgbà Ísírẹ́lì Ábúsálómù sì wí pé, Ǹjẹ́ pe Húṣáì ará Áríkì, àwa ó sì gbọ́ èyí tí ó wà lẹ́nu rẹ̀ pẹ̀lú Húṣáì sì dé ọ̀dọ̀ Ábúsálómù, Ábúsálómù sì wí fún un pé, Báyìí ni Áhítófélì wí, kí àwa ṣe bí ọ̀rọ̀ rẹ bí Bí ko bá sì tọ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ wí Húṣáì sì wí fún Ábúsálómù pé, Ìmọ̀ tí Áhítófélì gbà yìí, kò dára nísinsin yìí Húṣáì sì wí pé, Ìwọ mọ baba rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé alágbára ni wọ́n, wọ́n sì wà ní Kíkorò ọkàn bí àmọ̀tẹ́kùn tí a gbà ní ọmọ ni pápá baba rẹ sì jẹ́ jagunjagun ọkùnrin kì yóò bá àwọn ènìyàn náà gbé pọ̀ lóru Kíyèsí i, ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ nísinsin yìí ni ihò kan, tàbí ní ibòmíràn yóò sì ṣe, nígbà tí díẹ̀ nínú wọn bá kọ́ ṣubú, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóò sì wí pé, Ìparun sì ń bẹ́ nínú àwọn ènìyàn tí ń tọ Ábúsálómù lẹ́yìn Ẹni tí ó sì ṣe alágbára, tí ọkàn rẹ̀ sì dàbí ọkàn kìnnìun, yóò sì rẹ̀ ẹ́ nítorí gbogbo Ísírẹ́lì ti mọ̀ pé alágbára ni baba rẹ, àti pé, àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ jẹ́ alágbára Nítorí náà èmi dámọ̀ràn pé Kí gbogbo Ísírẹ́lì wọ́jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ, láti Dánì títí dé Bééríṣébà, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn létí òkun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àti pé, kí ìwọ tìkárarẹ ó lọ sí ogun náà Àwá ó sì yọ sí i níbikíbi tí àwa o gbé rí i, àwa ó sì yí i ká bí ìrì ti ń ṣẹ̀ sí ilẹ̀ àní, ọkàn kan kì yóò kù pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ Bí o bá sì bọ́ sí ìlú kan, gbogbo Ísírẹ́lì yóò mú okùn wá sí ìlú náà, àwa ó sì fà á lọ sí odo, títí a kì yóò fi rí òkúta kékeké kan níbẹ̀ Ábúsálómù àti gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wí pé, Ìmọ̀ Húṣáì ará Áríkì sàn ju ìmọ̀ Áhítófélì lọ! Nítorí Olúwa fẹ́ láti yí ìmọ̀ rere ti Áhítófélì po Nítorí kí Olúwa lè mú ibi wá sórí Ábúsálómù Húṣáì sì wí fún Sádókù àti fún Ábíátarì àwọn àlùfáà pé, Bàyìí ni Áhítófélì ti bá Ábúsálómù àti àwọn àgbà Ísírẹ́lì dámọ̀ràn báyìí lèmi sì báa dámọ̀ràn Nítorí náà yára ránṣẹ́ nísinsin yìí kí o sì sọ fún Dáfídì pé, Má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà lálẹ́ yìí, ṣùgbọ́n yára rékọjá kí a má báa gbé ọba mì, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ   Jónátanì àti Áhímásì sì dúró ní Énrógélì ọ̀dọ́mọdébìnrin kan sì lọ, ó sì sọ fún wọn, wọ́n sì lọ wọ́n sọ fún Dáfídì ọba nítorí pé kí a má báà rí wọn pé wọ́n wọ ìlú Ṣùgbọ́n ọdọmọdékùnrin kan rí wọn, ó sì wí fún Ábúsálómù ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì sì yára lọ kúrò, wọ́n sì wá sí ilé ọkùnrin kan ní Báhúrímù, ẹni tí ó ní kànga kan ní ọgbà rẹ̀, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ sí ibẹ̀ Obìnrin rẹ̀ sì mú nǹkán ó fi bo kanga náà, ó sì sá àgbàdo sórí rẹ̀, a kò sì mọ̀ Àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù sì tọ obìnrin náà wá sí ilé náà, wọ́n sì béèrè pé, Níbo ni Áhímásì àti Jónátanì gbé wà Obìnrin náà sì wí fún wọn pé, Wọ́n ti gòkè rékọjá ìṣàn odò náà Wọ́n sì wá wọn kiri, wọn kò sì rí wọn, wọ́n sì yípadà sí Jérúsálẹ́mù Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti lọ tán, àwọn ọkùnrin náà sì jáde kúrò nínú kànga, wọ́n sì lọ wọ́n sì rò fún Dáfídì ọba Wọ́n sọ fún Dáfídì pé, Dìde kí o sì gòkè odò kánkán nítorí pé bayìí ni Áhítófélì gbìmọ̀ sí ọ Dáfídì sì dìde, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì gòkè odò Jódánì kí ilẹ̀ tó mọ́, ènìyàn kò kù tí kò gòkè odò Jódánì Nígbà tí Áhítófélì sì ríi pé wọn kò fi ìmọ̀ tirẹ̀ ṣe, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ni gàárí, ó sì dìde, ó lọ ilé rẹ̀, ó sì palẹ̀ ilé rẹ̀ mọ̀, ó sì so, ó sì kú, a sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀ Ábúsálómù gbógun ti Dáfídì Dáfídì sì wá sí Mahánáímù, Ábúsálómù sì gòkè odò Jódánì, òun àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ Ábúsálómù sì fi Ámásà ṣe olórí ogun ní ipò Jóábù Ámásà ẹni tí í ṣe ọmọ ẹnìkan, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Itírà, ará Ísírẹ́lì, tí ó wọlé tọ Ábígáílì ọmọbìnrin Náhásì, arabìnrin Sérúíà, ìyá Jóábù Ísírẹ́lì àti Ábúsálómù sì dó ní ilẹ̀ Gílíádì Nígbà tí Dáfídì sì wá sí Mahánáímù, Ṣóbì ọmọ Nahásì ti Rábà tí àwọn ọmọ Ámónì, àti Mákírì ọmọ Ámíélì ti Lodebárì, àti Básíláì ará Gílíádì ti Rógélímù Mú àwọn àkéte, àti àwọn àwo, àti ìkòkò amọ̀, àti àlìkámà, àti ọkà, àti ìyẹ̀fun, àti àgbàdo díndín, àti ẹ̀wà, àti erèé, àti ẹ̀wà díndùn Àti oyin, àti òrí-àmọ́, àti àgùntàn, àti wàràǹkàsì màlúù, wá fún Dáfídì àti fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, láti jẹ nítorí tí wọ́n wí pé, Ebi ń pa àwọn ènìyàn, ó sì rẹ̀ wọ́n, òǹgbẹ sì ń gbẹ wọ́n ní ihà Wọ́n Pàdé Ogun Ní Igbó Éfúráímù Dáfídì sì ka àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì mú wọn jẹ balógun ẹgbẹgbẹ̀rún, àti balógun ọrọrún lórí wọn Dáfídì sì fi ìdámẹ́ta àwọn ènìyàn náà lé Jóábù lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ, àti ìdámẹ́ta lé Ábíṣáì ọmọ Serúíà àbúrò Jóábù lọ́wọ́ àti ìdàmẹ́ta lè Ítaì ará Gítì lọ́wọ́, Ọba sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, Nítòótọ́ èmi tìkárami yóò sì bá yín lọ pẹ̀lú Àwọn ènìyàn náà sì wí pé, Ìwọ kì yóò bá wa lọ nítorí pé bí àwa bá sá, wọn kì yóò náání wa, tàbí bí ó tílẹ̀ ṣe pé ìdajì wa kú, wọn kì yóò násní wa, nítorí pé ìwọ nìkan tó ẹgbàarún wa nítorí náà, ó sì dára kí ìwọ máa ràn wá lọ́wọ́ láti ìlú wá Ọba sì wí fún wọn pé, Èyí tí ó bá tọ́ lójú yin ni èmi ó ṣe Ọba sì dúró ní apákan ẹnu odi, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì jáde ní ọrọrún àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ọba sì pàṣẹ fún Jóábù àti Ábíṣáì àti Ítaì pé, Ẹ tọ́jú ọ̀dọ́mọkùnrin náà Ábúsálómù fún mi Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn balógun nítorí Ábúsálómù Àwọn ènìyàn náà sì jáde láti pàdé Ísírẹ́lì ní pápá ní igbó Éfúráímù ni wọ́n gbé pàdé ijà náà Níbẹ̀ ni a gbé pa àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì níwájú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó ṣubú lọ́jọ́ náà, àní ẹgbàáwá ènìyàn Ogun náà sì fọ́n káàkiri lórí gbogbo ilẹ̀ náà igbó náà sì pa ọ̀pọ̀ ènìyàn ju èyí tí idà pa lọ lọ́jọ́ náà Ábúsálómù sì pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì Ábúsálómù sì gun orí ìbaka kan, ìbaka náà sì gba abẹ́ ẹ̀ka ńlá igi óákù kan tí ó tóbi lọ, orí rẹ̀ sì kọ́ igi óákù náà òun sì rọ̀ sókè ní agbede-méjì ọ̀run àti ilẹ̀ ìbaka náà tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sì lọ kúrò Ọkùnrin kan sì rí i, ó sì wí fún Jóábù pé, Wò ó, èmi rí Ábúsálómù so rọ̀ láàrin igi óákù kan Jóábù sì wí fún ọkùnrin náà tí ó sọ fún un pé, Sá wò ó, ìwọ rí i, èéha ti ṣe tí ìwọ kò fi lù ú bolẹ̀ níbẹ̀ Èmi ìbá sì fún ọ ní ṣékélì fàdákà mẹ́wàá, àti àmùrè kan Ọkùnrin náà sì wí fún Jóábù pé, Bí èmi tilẹ̀ gba ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà sí ọwọ́ mí, èmi kì yóò fi ọwọ́ mi kan ọmọ ọba nítorí pé àwa gbọ́ nígbà tí ọba kìlọ̀ fún ìwọ àti Ábíṣáì, àti Ítaì, pé, Ẹ kíyèsí i, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọwọ́ kan ọ̀dọ́mọkùnrin náà Ábúsálómù Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ èmi ìbá ṣe sí ara mi nítorí pé kò sí ọ̀ràn kan tí ó pamọ́ fún ọba, ìwọ tìkárarẹ̀ ìbá sì kọjú ìjà sí mi pẹ̀lú Jóábù sì wí pé, Èmi kì yóò dúró bẹ́ẹ̀ níwájú rẹ Ó sì mú ọ̀kọ̀ mẹ́ta lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ́n gún Ábúsálómù ní ọkàn, nígbà tí ó sì wà láàyè ní agbede-méjì igi óákù náà Àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin mẹ́wàá tí ó máa ń ru ìhámọ́ra Jóábù sì yí Ábúsálómù ká, wọ́n sì kọlù ú, wọ́n sì pa á, Jóábù sì fun ìpè, àwọn ènìyàn náà sì yípadà láti máa lépa Ísírẹ́lì nítorí Jóábù ti pe àwọn ènìyàn náà padà Wọ́n sì gbé Ábúsálómù, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò ńlá kan ní igbó náà, wọ́n sì kó òkúta púpọ̀ jọ sí i lórí, gbogbo Ísírẹ́lì sì sá, olúkúlùkù sí inú àgọ́ rẹ̀ Ábúsálómù ní ìgbà ayé rẹ̀, sì mọ ọ̀wọ̀n kan fún ara rẹ̀, tí ń bẹ ní àfonífojì ọba nítorí tí ó wí pé, Èmi kò ní ọmọkùnrin tí yóò pa orúkọ mi mọ́ ní ìrántí òun sì pe ọ̀wọ̀n náà nípa orúkọ rẹ̀ a sì ń pè é títí di òní, ní ọ̀wọ́n Ábúsálómù Áhímásì ọmọ Sádókù sì wí pé, Jẹ́ kí èmi ó súré nísinsin yìí, kí èmi sì mú ìhìn tọ ọba lọ, bí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ̀ lára àwọn ọ̀ta rẹ̀ Jóábù sì wí fún un pé, Ìwọ kì yóò mù ìhìn lọ lónìí, ṣùgbọ́n ìwọ ó mú lọ ní ijọ́ mìíràn ṣùgbọ́n lónìí yìí ìwọ kì yóò mú ìhìn kan lọ, nítorí tí ọmọ Ọba ṣe aláìsí Jóábù sì wí fún Kúṣì pé, Lọ, kí ìwọ ro ohun tí ìwọ rí fún ọba Kúṣì sì wólẹ̀ fún Jóábù ó sì sáré Áhímásì ọmọ Sádókù sì tún wí fún Jóábù pé, Jọ̀wọ́, bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré tẹ Kúṣì lẹ́yìn Jóábù sì bi í pé, Nítorí kín ni ìwọ ó ṣe sáré, ọmọ mi, ìwọ kò ri pé kò sí ìhìn rere kan tí ìwọ ó mú lọ Ó sì wí pé, Bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré Ó sì wí fún un pé, Sáré! Áhímásì sì sáré ní ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀, ó sì sáré kọjá Kúṣì Dáfídì sì jókòó lẹ́nu odì láàrin ìlẹ̀kùn méjì Álóre sì gòkè òrùlé bodè lórí odi, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wò, wò ó, ọkùnrin kan ń sáré òun nìkan Álóre náà sì kígbe, ó sì wí fún ọba Ọba sì wí pé, Bí ó bá ṣe òun nìkan ni, ìhìn rere ń bẹ lẹ́nu rẹ̀ Òun sì ń súnmọ́ tòsí Álóre náà sì rí ọkùnrin mìíràn tí ń sáré Alóre sì kọ sí ẹni tí ń ṣọ́ bodè, ó sì wí pe, Wò ó, ọkùnrin kan ń sáré òun nìkan Ọba sì wí pé, Èyí náà pẹ̀lú ń mú ìhìn rere wá Álóre náà sì wí pé, Èmi wo ìsáre ẹni tí ó wà níwájú ó dàbí ìsáré Áhímásì ọmọ Sádókù Ọba sì wí pé, Ènìyàn re ni, ó sì ń mú ìhìn rere wá! Áhímásì sì dé, ó sì wí fún ọba pé, Àlàáfíà! Ó sì wólẹ̀ fún ọba, ó dojúbolẹ̀ ó sì wí pé, Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó fi àwọn ọkùnrin tí ó gbé ọwọ́ wọn sókè sí Olúwa mi ọba lé ọ lọ́wọ́ Ọba sì béèrè pé, Àlàáfíà ha wà fún Ábúsálómù, ọmọdékùnrin náà bí Áhímásì sì dáhùn pé, Nígbà tí Jóábù rán ìránṣẹ́ ọba, àti èmi ìránṣẹ́ rẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ìdí rẹ̀ Ọba sì wí fún un pé, Yípadà kí o sì dúró nìhìn-ín Òun sì yípadà, ó sì dúró jẹ́ẹ́ Sì wò ó, Kúṣì sì wí pé, Ìhìnrere fún Olúwa mi ọba nítorí tí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ lónìí lára gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ Ọba sì bi Kúṣì pé, Àlàáfíà kọ́ Ábúsálómù ọ̀dọ́mọdékùnrin náà wá bí Kúṣì sì dáhùn pe, Kí àwọn ọ̀ta Olúwa mi ọba, àti gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ ní ibi, rí bí ọ̀dọ́mọdékùnrin náà Ọba sì kẹ́dùn púpọ̀ ó sì gòkè lọ, sí yàrá tí ó wà lórí òkè ibodè, ó sì sunkún bayìí ni ó sì ń wí bí ó ti ń lọ, Ọmọ mi Ábúsálómù! Ọmọ mi! Ọmọ mí Ábúsálómù! Áì! Ìbáṣepé èmi ni ó kú ní ipò rẹ̀! Ábúsálómù ọmọ mi, ọmọ mi! Jóábù Bá Dáfídì Wí Gidigidi A sì rò fún Jóábù pe, Wò ó, ọba ń sunkun, ó sì ń gbààwẹ̀ fún Ábúsálómù Ìṣẹ́gun ijọ́ náà sì di ààwẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, nítorí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ní ijọ́ náà bí inú ọba ti bàjẹ́ nítorí ọmọ rẹ̀ Àwọn ènìyàn náà sì yọ́ lọ sí ìlú ní ijọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àwọn bí ènìyàn tí a dójútì ṣe máa ń yọ́ lọ nígbà tí wọ́n bá sá lójú ìjà Ọba sì bo ojú rẹ̀, ọba sì kígbe ní ohùn rara pé, Áì! Ọmọ mi Ábúsálómù! Ábúsálómù ọmọ mi, ọmọ mi! Jóábù sì wọ inú ile tọ ọba lọ, ó sì wí pé, Ìwọ dójúti gbogbo àwọn ìránṣẹ rẹ lónìí, àwọn tí ó gba ẹ̀mí rẹ̀ là lónìí, àti ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti ti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, àti àwọn aya rẹ̀, àti ẹ̀mí àwọn obìnrin rẹ Nítorí pé ìwọ fẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ sì kóríra àwọn ọ̀rẹ́ rẹ Nítorí tí ìwọ wí lónìí pé, Ìwọ kò náání àwọn ọmọ ọba tàbí àwọn ìránṣẹ́ èmi sì rí lónìí pé, ìbáṣe pé Ábúsálómù wà láàyè, kí gbogbo wa sì kú lónìí, ǹjẹ́ ìbá dùn mọ́ ọ gidigidi Sì dìde nísinsin yìí, lọ, kí o sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ nítorí pé èmi fi Olúwa búra, bí ìwọ kò bá lọ, ẹnìkan kì yóò bá ọ dúró ni alẹ́ yìí èyí ni yóò sì burú fún ọ ju gbogbo ibi tí ojú rẹ ti ń rí láti ìgbà èwe rẹ wá títí ó fi di ìsinsinyìí Ọba sì dìde, ó sì jókòó ní ẹnu ọ̀nà, Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, Wò ó, ọba jókòó lẹ́nu ọ̀nà Gbogbo ènìyàn sì wá sí iwájú Ọba nítorí pé, Ísírẹ́lì ti sá, olúkúlukú sí àgọ́ rẹ̀ Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń bà ara wọn jà nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, pé, Ọba ti gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ó sì ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì òun sì wá sá kúrò ní ìlú nítorí Ábúsálómù Ábúsálómù, tí àwa fi jọba lórí wa sì kú ní ogun ǹjẹ́ èéṣe tí ẹ̀yín fi dákẹ́ tí ẹ̀yin kò sì sọ̀rọ̀ kan láti mú ọba padà wá Dáfídì ọba sì ránṣẹ́ sí Sádókù, àti sí Ábíátarì àwọn àlùfáà pé, Sọ fún àwọn àgbà Júdà, pé, Èéṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá sí ilé rẹ̀ Ọ̀rọ̀ gbogbo Ísírẹ́lì sì ti dé ọ̀dọ̀ ọba àní ní ilé rẹ̀ Ẹ̀yin ni ara mi, ẹ̀yin ni egungun mi, àti ẹran ara mi èésì ti ṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá Kí ẹ̀yin sì wí fún Ámásà pé, Egungun àti ẹran ara mi kọ́ ni ìwọ jẹ́ bí Kí Ọlọ́run ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ kò ba ṣe olórí ogun níwájú mi títí, ní ipò Jóábù   Òun sì yí gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà lọ́kàn padà àní bí ọkàn ènìyàn kan wọ́n sì ránṣẹ́ sí ọba, pé, Ìwọ padà àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ Ọba sì padà, o sì wá sí odò Jódánì, Júdà sì wá sí Gílígálì láti lọ pàdé ọba, àti láti mú ọba kọjá odò Jódánì Ṣíméhì ọmọ Gérà, ará Bẹ́ńjámínì ti Báhúrímù, ó yára ó sì bá àwọn ọkùnrin Júdà sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Dáfídì ọba Ẹgbẹ̀rún ọmọkùnrin sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì, Ṣíbà ìránṣẹ́ ilé Ṣọ́ọ̀lù, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún àti ogún ìránṣẹ́ sì pẹ̀lú rẹ̀ wọ́n sì gòkè odò Jódánì ṣáájú ọba Ọkọ̀ èrò kan ti rékọjá láti kó àwọn ènìyàn ilé ọba sí òkè, àti láti ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀ Ṣíméhì ọmọ Gérà wólẹ̀ Ó sì dojúbolẹ̀ níwájú ọba, bí ó tí gòkè odò Jódánì Ó sì wí fún ọba pé, Kí Olúwa mi ó má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ sí mi lọ́rùn, má sì ṣe rántí àfojúdi tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ni ọjọ́ tí Olúwa mi ọba jáde ní Jérúsálẹ́mù, kí ọba má sì fi sí inú Nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé èmi ti ṣẹ̀ sì wòó, mo wá lónìí yìí, ẹni àkọ́kọ́ ní gbogbo ìdílé Jósẹ́fù tí yóò sọ̀kalẹ̀ wá pàdé Olúwa mi ọba Ṣùgbọ́n Ábíṣáì ọmọ Serúíà dáhùn ó sì wí pé, Kò há tọ́ kí a pa Síméì nítorí èyí Nítorí pé òun ti bú ẹni àmì òróró Olúwa Dáfídì sì wí pé, Kí ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Serúíà tí ẹ dàbí ọ̀ta fún mi lónìí A há lè pa ènìyàn kan lónìí ní Ísírẹ́lì Tàbí èmi kò ha mọ̀ pé lónìí èmi ni ọba Ísírẹ́lì Ọba sì wí fún Ṣíméhì pé, Ìwọ kì yóò kú! Ọba sì búra fún un Méfíbóṣetì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì sọ̀kalẹ̀ láti wá pàdé ọba, kò wẹ ẹṣẹ̀ rẹ̀, kò sí tọ́ irungbọ̀n rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fọ aṣọ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ọba ti jáde títí ó fi di ọjọ́ tí ó fi padà ní àlàáfíà Nígbà tí òun sì wá sí Jérúsálẹ́mù láti pàdé ọba, ọba sì wí fún un pé, Èéṣe tí ìwọ kò fi bá mi lọ, Méfíbóṣétì Òun sì dáhùn wí pé, Olúwa mi, Ọba, ìránṣẹ́ mi ni ó tàn mí, nítorí ìránṣẹ́ rẹ wí fún un pé, Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi èmi ó gùn ún, èmi ó sì tọ ọba lọ Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ yarọ Ó sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí ìránṣẹ́ rẹ, fún Olúwa mi ọba, ṣùgbọ́n bí áńgẹ́lì Ọlọ́run ni Olúwa mi ọba rí nítorí náà ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ Nítorí pé gbogbo ilé baba mi bí òkú ènìyàn ni wọ́n sáà rí níwájú Olúwa mi ọba ìwọ sì fi ipò fún ìránṣẹ́ rẹ láàrin àwọn tí ó ń jẹ́un ní ibi oúnjẹ́ Nítorí náà àre kín ni èmi ní tí èmi yóò fi máa ké pe ọba síbẹ̀ Ọba sì wí fún un pé, Èéṣe tí ìwọ fi ń sọ ọ̀ràn ara rẹ fún mi èmi sáà ti wí pé, kí ìwọ àti Ṣíbà pín ilẹ̀ náà Méfíbóṣétì sì wí fún ọba pé, Jẹ́ kí ó mú gbogbo rẹ̀, kí Olúwa mi ọba sáà ti padà bọ̀ wá ilé rẹ̀ ni àlàáfíà Básíláì ará Gílíádì sì sọ̀kalẹ̀ láti Rogelímù wá, ó sì bá ọba gòkè odò Jódánì, láti ṣe ìkẹ́ rẹ̀ sí ìkọjá odò Jódánì Básíláì sì jẹ́ arúgbó ọkùnrìn gidigidi, ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sì ni ó sì pèsè ohun jíjẹ fún ọba nígbà tí ó ti wà ní Máhánáímù nítorí pé ọkùnrin ọlọ́lá ni òun ń ṣe Ọba sì wí fún Básíláì pé, Ìwọ wá bá mi gòkè odò, èmi ó sì máa pésè fún ọ ní Jérúsálẹ́mù Básíláì sì wí fún ọba pé, Ọjọ́ mélòó ni ọdún ẹ̀mí mi kù, tí èmi ó fi bá ọba gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù Ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sáà ni èmi lónìí ǹjẹ́ èmi mọ ìyàtọ̀ nínú rere àti búburú Ǹjẹ́ ìránṣẹ́ rẹ ló mọ adùn ohun tí òun ń jẹ tàbí ohun ti òun ń mu bí Èmi tún lè mọ adùn ohùn àwọn ọkùnrin tí ń kọrin àti àwọn obìnrin tí ń kọ́rin bí, ǹjẹ́ nítorí kínni ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe jẹ́ ìyọnu síbẹ̀ fún Olúwa mi ọba Ìránṣẹ́ rẹ yóò sì sin ọba lọ díẹ̀ gòkè odò Jódánì èésì ṣe tí ọba yóò fi san ẹ̀san yìí fún mi Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ padà, èmi ó sì kú ní ìlú mi, a ó sì sin mí ní ibojì baba àti ìyá mi Sì wo Kimhámù ìránṣẹ́ rẹ, yóò bá Olúwa mi ọba gòkè ìwọ ó sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ fún un Ọba sì dáhùn wí pé, Kímhámù yóò bá mi gòkè, èmi ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀ fún un ohunkóhun tí ìwọ bá sì béèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó ṣeé fún ọ Gbogbo àwọn ènìyàn sì gòkè odò Jódánì ọba sì gòkè ọba sì fi ẹnu ko Básíláì lẹ́nu, ó sì súre fún un òun sì padà sí ilé rẹ̀ Ọba sì ń lọ́ sí Gílígálì, Kímhámù sì ń bà a lọ, gbogbo àwọn ènìyàn Júdà sì ń ṣe ìkẹ́ ọba, àti ààbò àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì Sì wò ó, gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì tọ ọba wá, wọ́n sì wí fún ọba pé, Èéṣe tí àwọn arákùnrin wa àwọn ọkùnrin Júdà fi jí ọ kúrò, tí wọ́n sì fi mú ọba àti àwọn ará ilé rẹ̀ gòkè odò Jódánì, àti gbogbo àwọn ènìyàn Dáfídì pẹ̀lú rẹ Gbogbo ọkùnrin Júdà sì dá àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì lóhùn pé, Nítorí pé ọba bá wa tan ni èéṣe tí ẹ̀yin fi bínú nítorí ọ̀ràn yìí Àwa jẹ nínú òúnjẹ ọba rárá bí Tàbí ó fi ẹ̀bùn kan fún wa bí Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì náà sì dá àwọn ọkùnrin Júdà lóhùn pé, Àwa ní ipá mẹ́wàá nínú ọba, àwa sì ní nínú Dáfídì jù yín lọ, èésì ṣe tí ẹ̀yin kò fi kà wá sí, tí ìmọ̀ wa kò fi ṣáájú láti mú ọba wa padà Ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Júdà sì le ju ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì A Yan Dáfídì Ní Ọba Júdà Lẹ́yìn àkókò yìí, Dáfídì wádìí lọ́wọ́ Olúwa Ó sì béèrè pé, Ṣé èmi lè gòkè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú Júdà Olúwa sì wí pé, Gòkè lọ Dáfídì sì béèrè pé, Ní ibo ni kí èmi kí ó lọ Olúwa sì dáa lóhùn pé, Sí Hébúrónì Nígbà náà ni Dáfídì gòkè lọ ṣíbẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ méjì Áhínóámù ará Jésérẹ́lì, àti Ábígáílì obìnrin opó Nábálì ti Kámẹ́lì Dáfídì sì mú àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ní Hébúrónì àti ìlú rẹ̀ mìíràn Nígbà náà àwọn ọkùnrin ará Júdà wá sí Hébúrónì, níbẹ̀ ni wọ́n ti fi àmì òróró yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Júdà Nígbà tí wọ́n sọ fún Dáfídì pé, àwọn ọkùnrin ti Jábésì Gílíádì ni ó sin òkú Ṣọ́ọ̀lù, Ó rán oníṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin Jábésì Gílíádì láti sọ fún wọn pé, Olúwa bùkún un yín fún fífi inú rere yín hàn sí Ṣọ́ọ̀lù ọ̀gá yín nípa sí sin ín Kí Olúwa kí ó fi inú rere àti òtítọ́ fún un yín, èmi náà yóò sì san oore yìí fún un yín, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ẹ mú ara yín le, kí ẹ sì ní ìgboyà, nítorí Ṣọ́ọ̀lù ọba yín ti kú, ilé Júdà sì ti fi àmì òróró yàn mí ní ọba lórí wọn Lákòókò yìí, Ábínérì ọmọ Nérì olórí ogun Ṣọ́ọ̀lù ti mú Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù, ó sì mú un kọjá sí Máhánáímù Ó sì fi jẹ ọba lórí Gílíádì Áṣúrì àti Jésérẹ́lì àti lórí Éfúráímù àti lórí Bẹ́ńjámínì àti lórí gbogbo Ísírẹ́lì Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí ó jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì jọba fún ọdún méjì Ilé Júdà sì ń tọ Dáfídì lẹ́yìn Gbogbo àkókò tí Dáfídì fi jọba ní Hébúrónì lórí ilé Júdà sì jẹ́ ọdún méje àti oṣù mẹ́fà Ábínérì ọmọ Nérì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ti Íṣíbóṣetì ọmọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù kúrò ní Máhánáímù, wọ́n sì lọ sí Gíbíónì Jóábù ọmọ Sérúíà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Dáfídì jáde lọ láti lọ bá wọn ní adágún Gíbíónì Ẹgbẹ́ kan sì jókòó ní apá kan adágún, àti ẹgbẹ́ kejì ní apá kejì adágún Nígbà náà, Ábínérì sọ fún Jóábù pé, Jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ó dìde láti bá ara wọn jà níwájú wa Jóábù sì dáhùn pé, Ó dára, jẹ́ kí wọ́n ṣe é, Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dìde sókè, a sì kà wọ́n sí ọkùnrin méjìlá fún Bẹ́ńjámínì àti Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù àti méjìlá fún Dáfídì Nígbà náà olúkúlùkù ọkùnrin gbá ẹnìkejì rẹ̀ mú ní orí, ó sì fi idà gún ẹnìkejì rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀ papọ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ibẹ̀ ni Gíbíónì ti à ń pè ni Helikatihu Hasurímù Ogun náà ní ọjọ́ náà gbóná Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì ṣẹ́gun Ábínérì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì Àwọn ọmọkùnrin Serúíà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni ó wà níbẹ̀ Jóábù, Ábíṣáì àti Ásáhélì Nísinsìnyìí ẹṣẹ̀ Ásáhélì sì fẹ́rẹ̀ bí ẹṣẹ̀ àgbọ̀nrín tí ó wà ní pápá Ó ń lé Ábínérì, kò sì yípadà sí ọ̀tún tàbí sí òsì bí ó ti ń lé e Ábínérì bojú wo ẹ̀yìn rẹ̀, Ó sì béèrè pé, Ṣé ìwọ Ásáhélì ni Ó dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni, Nígbà náà, Ábínérì sọ fún un pé, Yípadà sí ọ̀tún tàbí òsì mú ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kí o sì bọ́ ìhámọ́ra rẹ Ṣùgbọ́n Ásáhélì kọ̀ láti dẹ́kun lílépa rẹ̀ Ábínérì tún kìlọ̀ fún Ásáhélì, Dẹ́kun lílépa mi! Èéṣe tí èmi yóò fi lù ọ́ bolẹ̀ Báwo ni èmi yóò ti wo arákùnrin rẹ Jóábù lójú Ṣùgbọ́n ó sí kọ̀ láti padà, Ábínérì sì fi òdì ọ̀kọ̀ gún un lábẹ́ inú, ọ̀kọ̀ náà sì jáde ní ẹ̀yìn rẹ̀ òun sì ṣubú lulẹ̀ níbẹ́, ó sì kú ní ibi kan náà ó sí ṣe gbogbo ènìyàn tí ó dé ibi tí Ásáhélì gbé ṣúbú si, tí ó sì kú, sì dúró jẹ́ Jóábù àti Ábíṣáì sì lépa Ábínérì òòrùn sì wọ̀, wọ́n sì dé òkè ti Ámímà tí o wà níwájú Gíà lọ́nà ijù Gíbíónì Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì kó ara wọn jọ wọ́n tẹ̀lé Ábínérì, wọ́n sì wá di ẹgbẹ́ kan, wọ́n sì dúró lórí òkè kan Ábínérì sì pe Jóábù, ó sì bi í léèrè pé, Idà yóò máa parún títí láéláé bí Ǹjẹ́ ìwọ kòì tí ì mọ̀ pé yóò korò nikẹyìn Ǹjẹ́ yóò ha ti pẹ́ tó kí ìwọ tó sọ fún àwọn ènìyàn náà, kí wọ́n dẹ́kun láti máa lépa arákùnrin wọn Jóábù sì wí pé, Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, bí kò ṣe bí ìwọ ti wí, nítòótọ́ ní òwúrọ̀ ni àwọn ènìyàn náà ìbá padà lẹ́yìn arákùnrin wọn Jóábù sì fọ́n ipè, gbogbo ènìyàn sì dúró jẹ́ẹ́, wọn kò sì lépa Ísírẹ́lì mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì tún jà mọ́ Ábínérì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì fi gbogbo òru náà rìn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì kọjá Jọ́dánì, wọ́n sì rìn ní gbogbo Bítírónì, wọ́n sì wá sí Mahanáímù Jóábù sì dẹ́kún àti máa tọ Ábínérì lẹ́yìn ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ, ènìyàn mọ́kándínlógún ni ó kú pẹ̀lú Áṣáhélì nínú àwọn ìránṣẹ Dáfídì Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ Dáfídì sì pá nínú àwọn ènìyàn Bẹ́ńjámínì nínú àwọn ọmọkùnrin Ábínérì òjìdínní-rinwó ènìyàn Wọ́n si gbé Ásáhélì wọ́n sì sinín sínú ibojì baba rẹ̀ tí ó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Jóábù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi gbogbo òru náà rìn, ilẹ̀ sì mọ́ wọn sí Hébírónì Ìṣọ̀tẹ̀ Sí Dáfídì Ọkùnrin Bélíálì kan sì ń bẹ níbẹ̀ orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣébà ọmọ Bíkírì ará Bẹ́ńjámínì ó sì fún ìpè ó sì wí pé, Àwa kò ní ipa nínú Dáfídì, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ni ìní nínú ọmọ Jésè! Kí olúkúlùkù ọkùnrin lọ sí àgọ́ rẹ̀, ẹ̀yin Ísírẹ́lì! Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì lọ kúrò lẹ́yìn Dáfídì, wọ́n sì ń tọ́ Ṣébà ọmọ Bíkírì lẹ́yìn ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Júdà sì fi ara mọ́ ọba wọn láti odò Jódánì wá títí ó fi dé Jérúsálẹ́mù Dáfídì sì wà ní ilé rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù ọba sì mú àwọn obìnrin mẹ́wàá tí í ṣe àlè rẹ̀, àwọn tí ó ti fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ile, Ó sì há wọn mọ́ ilé, ó sì ń bọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò sì tún wọlé tọ̀ wọ́n mọ́ A sì ṣé wọn mọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì wà bí opó Ọba sì wí fún Ámásà pé, Pè àwọn ọkùnrin Júdà fún mi níwọn ijọ́ mẹ́ta òní, kí ìwọ náà kí o sì wà níhìnyìí Ámásà sì lọ láti pe àwọn ọkùnrin Júdà ṣùgbọ́n ó sì dúró pẹ́ ju àkókò tí a fi fún un Dáfídì sì wí fún Ábíṣáì pé, Nísinsinyìí Ṣébè ọmọ Bíkírì yóò ṣe wá ní ibi ju ti Ábúsálómù lọ ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má baà rí ìlú olódì wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa Àwọn ọmọkùnrin Jóábù sì jáde tọ̀ ọ́ lọ, àti àwọn Kérétì, àti àwọn Pélétì, àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára wọ́n sì ti Jérúsálẹ́mù jáde lọ, láti lépa Ṣábà ọmọ Bíkírì Nígbà tí wọ́n dé ibi òkútà ńlá tí ó wà ní Gíbíónì, Ámásà sì ṣáájú wọn, Jóábù sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde Jóábù sì bi Ámásà léèrè pé, Ara rẹ kò le bí, ìwọ arákùnrin mi Jóábù sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, di Ámásà ní irungbọ̀n mú láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu Ṣùgbọ́n Ámásà kò sì kíyèsí idà tí ń bẹ lọ́wọ́ Jóábù bẹ́ẹ̀ ni òun sì fi gún un ní ikùn, ìfun rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀, òun kò sì tún gún un mọ́ ó sì kú Jóábù àti Ábíṣáì arákùnrin rẹ̀ sì lépa Ṣébà ọmọ Bíkírì Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Jóábù sì dúró tì í, ó sì wí pé, Ta ni ẹni tí ó fẹ́ràn Jóábù Ta ni ó sì ń ṣe ti Dáfídì, kí ó máa tọ Jóábù lẹ́yìn Ámásà sì ń yíràá nínú ẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀nà Ọkùnrin náà sì ríi pé gbogbo ènìyàn sì dúró tì í, ó sì gbé Ámásà kúrò lójú ọ̀nà lọ sínú ìgbẹ́, ó sì fi aṣọ bò ó, nígbà tí ó rí i pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, á dúró Nígbà tí ó sì gbé e kúrò lójú ọ̀nà gbogbo ènìyàn sì tọ Jóábù lẹ́yìn láti lépa Ṣébà ọmọ Bíkírì Ó kọjá nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì sí Ábélì ti Bẹti Máákà, àti gbogbo àwọn ará Bérítì wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ̀lú Wọ́n wá, wọ́n sì dó tì í ní Ábélì tí Bẹti Máákà, wọ́n sì mọ odí ti ìlú náà, odi náà sì dúró ti odi ìlú náà, gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ Jóábù sì ń gbìyànjú láti wó ògiri náà lulẹ̀ Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan sì kígbe sókè láti ìlú náà wá pé, Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀! Èmi bẹ̀ yín, ẹsọ fún Jóábù pé Súnmọ́ ìhìnyìí èmi ó sì bá a sọ̀rọ̀ Nígbà tí òun sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, obìnrin náà sì wí pé, Ìwọ ni Jóábù bí Òun sì dáhùn wí pé, Èmi náà ni Obìnrin náà sì wí fún un pé, Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́-bìnrin rẹ Òun sì dáhùn wí pé, Èmi ń gbọ́ Ó sì sọ̀rọ̀ wí pé, Wọ́n ti ń wí ṣáájú pé, Níti bíbéèrè, wọn ó béèrè ní Ábélì bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì parí ọ̀ràn náà Èmi ni ọ̀kan nínú àwọn ẹni àlàáfíà àti tòótọ́ ní Ísírẹ́lì ìwọ ń wá ọ̀nà láti pa ìlú kan run tí ó jẹ́ ìyá ní Ísírẹ́lì èéṣe tí ìwọ ó fi gbé ìní Olúwa mì Jóábù sì dáhùn wí pé, Kí a má rí i, kí a má rí i lọ́dọ̀ mi pé èmi gbé mì tàbí èmi sì parun Ọ̀ràn náà kò sì rí bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti òkè Éfúráímù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣébà, ọmọ Bíkírì, ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sòkè sí ọba, àní sí Dáfídì fi òun nìkanṣoṣo lé wa lọ́wọ́, èmi ó sì fi ìlú sílẹ̀ Obìnrin náà sì wí fún Jóábù pé, Wò ó, orí rẹ̀ ni a ó sì sọ láti inú odì wá Obìnrin náà sì mú ìmọ́ran rẹ̀ tọ gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì bẹ Ṣébà ọmọ Bíkírì lórí, wọ́n sì sọ ọ́ sí Jóábù Òun sì fún ìpè, wọ́n sì túká sọ́dọ̀ ọba Jóábù sì ni olórí gbogbo ogun Ísírẹ́lì Bénáyà ọmọ Jéhóiádà sì jẹ́ olórí àwọn Kérétì, àti ti àwọn Pélétì Ádórámù sì jẹ́ olórí àwọn agbowó òde Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì sì jẹ́ olùkọsílẹ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú Ṣéfà sì jẹ́ akọ̀wé Sádókù àti Ábíátarì sì ni àwọn àlùfáà Írà pẹ̀lú, ará Jáírì ni ń ṣe àlùfáà lọ́dọ̀ Dáfídì Àwọn Ará Gíbíónì Gba Ẹ̀san Ìyàn kan sì mú lọ́jọ́ Dáfídì ní ọdún mẹ́ta, láti ọdún dé ọdún Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa , Olúwa sì wí pé, Nítorí ti Ṣọ́ọ̀lù ni, àti nítorí ilé rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ó pa àwọn ará Gíbíónì Ọba sì pe àwọn ará Gíbíónì, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ àwọn ará Gíbíónì kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí ó kù nínú àwọn ọmọ Ámórì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti búra fún wọn Ṣọ́ọ̀lù sì ń wá ọ̀nà àti pa wọ́n ní ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà Dáfídì sì bi àwọn ará Gíbíónì léèrè pé, Kí ni èmi ó ṣe fún un yín Àti kìn ni èmi ó fi ṣe ètùtù, kí ẹ̀yin lè súre fún ilẹ̀ ìní Olúwa Àwọn ará Gíbíónì sì wí fún un pé, Kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà láàrin wa àti Ṣọ́ọ̀lù tàbí ìdílé rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fẹ́ kí ẹ pa ẹnìkan ní Ísírẹ́lì Dáfídì sì wí pé, Èyí tí ẹ̀yin bá wí ni èmi ó ṣe Wọ́n sì wí fún ọba pé, Ọkùnrin tí ó run wá, tí ó sì rò láti pa wá rẹ́ ki a má kù níbikíbi nínú gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì Mú ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wá, àwa ó sì so wọ́n rọ̀ fún Olúwa ní Gíbéà ti Ṣọ́ọ̀lù ẹni tí Olúwa ti yàn Ọba sì wí pé, Èmi ó fi wọ́n fún yín Ṣùgbọ́n Ọba dá Méfíbóṣétì sí, ọmọ Jónátanì, ọmọ Ṣọ́ọ̀lù, nítorí ìbúra Olúwa tí ó wà láàrin Dáfídì àti Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rísípà ọmọbìnrin Áíyà bí fún Ṣọ́ọ̀lù, àní Ámónì àti Méfíbóṣétì àwọn ọmọkùnrin máràrùn ti Mérábù, ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù, àwọn tí ó bí fún Ádíríélì ọmọ Básílíà ará Méhólátì Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Gíbéà lọ́wọ́, wọ́n sì so wọ́n rọ̀ lórí òkè níwájú Olúwa àwọn méjèèjì sì ṣubú lẹ́ẹ̀kan, a sì pa wọ́n ní ìgbà ìkórè, ní ìbẹ̀rẹ̀, ìkórè ọkà-báálì Rísípà ọmọbìnrin Áíyà sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sán-an, tàbí àwọn ẹranko ìgbẹ́ lóru A sì ro èyí, tí Rísípà ọmọbìnrin Áíyà obìnrin Ṣọ́ọ̀lù ṣe, fún Dáfídì Dáfídì sì lọ ó sì kó egungun Ṣọ́ọ̀lù, àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jábéṣì-Gíléádì, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Bẹti-Sánì, níbi tí àwọn Fílístínì gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Fílístínì pa Sọ́ọ̀lù ní Gílíbóà Ó sì mú egungun Sọ́ọ̀lù àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ láti ibẹ̀ náà wá wọ́n sì kó egungun àwọn tí a ti so rọ̀ jọ Wọ́n sì sin egungun Sọ́ọ̀lù àti ti Jònátánì ọmọ rẹ̀ ní ilé Bẹ́ńjámínì, ní Sélà, nínú ibojì Kíṣì baba rẹ̀ wọ́n sì ṣe gbogbo èyí tí ọba paláṣẹ lẹ́yìn èyí ni Ọlọ́run si gba ẹ̀bẹ̀ nítorí ilẹ̀ náà Ogun sì tún wà láàrin àwọn Fílístínì àti Ísírẹ́lì Dáfídì sì sọ̀kalẹ̀, àti àwọn ìránṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bá àwọn Fílístínì jà ó sì rẹ Dáfídì Iṣibi-bénóbù sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òmìrán, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀dúnrún ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dáfídì Ṣùgbọ́n Ábíṣáì ọmọ Sérúíà ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Fílístínì náà, ó sì paá, Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì búra fún un pé, Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí iwọ má ṣe pa iná Ísírẹ́lì Lẹ́yìn èyí, ìjà kan sì tún wà láàrin àwọn Ísírẹ́lì àti àwọn Fílístínì ní Góbù nígbà náà ni Síbékáì ará Húṣà pa Sáfù, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú àwọn òmìrán Ìjà kan sì tún wà ní Góbù láàrin àwọn Ísírẹ́lì àti àwọn Fílístínì, Élíhánánì ọmọ Jáírì ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù sì pa arákùnrin Gòláyátì, ará Gátì, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ dàbí ìdúbú igi tí a fi ń hun aṣọ Ìjà kan sì tún wà ní Gátì, ọkùnrin kan sì wà tí ó ga púpọ̀, ó sì ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ kan, àti ọmọ ẹṣẹ̀ mẹ́fà ní ẹṣẹ̀ kan, àpapọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́rìnlélógún a sì bí òun náà ní òmìrán Nígbà tí òun sì pe Ísírẹ́lì ní ìjà Jónátanì ọmọ Ṣíméhì arákùnrin Dáfídì sì pa á Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ni a bí ní òmìrán ní Gátì, wọ́n sì ti ọwọ́ Dáfídì ṣubú àti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ Orin Ìyìn Dáfídì Dáfídì sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí Olúwa ní ọjọ́ tí Olúwa gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù Ó sì wí pé, Olúwa ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò, àti ìwọ ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi, àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá Èmi képe Olúwa , tí ó yẹ láti máa yìn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí Ọ̀já isà-òkú yí mi káàkiri ìkẹ́kùn ikú dojú kọ mí Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé Olúwa , èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi Ó sí gbóhùn mi láti tẹ́ḿpìlì rẹ̀ igbe mí wọ etí rẹ̀ Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì, ó sì mì, nítorí tí ó bínú Èéfín sì jáde láti ihò-imú rẹ̀ wá iná láti ẹnu rẹ̀ wá, ó sì ń jónirun, ẹ̀yín sì ń ràn nípasẹ rẹ̀ Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀ òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́ Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi, àní ìsúdudu ìkùukùu àwọ̀n sánmà Nípaṣẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀ ẹ̀yín-iná ràn Olúwa sán ààrá láti ọ̀run wá, ọ̀gá ogo jùlọ sì fọhùn rẹ̀ Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn, ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn, nípa ìbáwí Olúwa , nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀ Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi ṣùgbọ́n Olúwa ni aláfẹ̀hìntì mi Ó sì mú mi wá sí àyè ńlá ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi Olúwa sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi Nítorí pé èmi pa ọ̀nà Olúwa mọ́, èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn Èmi sì wà nínú ìwà-títọ́ sí í, èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi Olúwa sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà-mímọ́ mi níwájú rẹ̀ Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú, àti fún ẹni-ìdúró-ṣinṣin ní òdodo ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní ìdúró-ṣinṣin ní òdodo Fún onínú-funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun àti fún ẹni-wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́ Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, Olúwa Olúwa yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárin ogun kọjá nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti dán wò Òun sì ni aṣà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára, ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́ Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹṣẹ̀ àgbọ̀nrín ó sì mú mi dúró ní ibi gígá mi Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà tóbẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ Ìwọ sì ti fún mi ní àsà ìgbàlà rẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá Ìwọ sì fi àyè ńlá sí abẹ́ ìṣísẹ̀ mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀ Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n, èmi kò pẹ̀yìndà títí èmi fi run wọ́n Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn, wọn kò sì le dìde mọ́ wọ́n ṣubú lábẹ́ mi Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà àwọn tí ó ti dìde sí mi ni ìwọ sì ti tẹ̀ lórí ba fún mi Ìwọ sì mú àwọn ọ̀ta mi pẹ̀yìndà fún mi, èmi ó sì pa àwọn tí ó kórira mi run Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n wọ́n wo Olúwa , ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi, ìwọ pá mí mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè Àwọn ènìyàn tí èmi kòì tí mọ̀ yóò máa sìn mí Àwọn àlejò wá láti tẹríba fún mi bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọn á sì gbọ́ tèmi Àyà yóò pá àwọn àlejò, wọn ó sì fi ìbẹ̀rù sá kúrò níbi kọ́lọ́fín wọn Olúwa ń bẹ́ olùbùkún sì ni àpáta mi! Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi, àti ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta mi Ìwọ sì gbé mi sókè ju àwọn tí ó dìde sí mi lọ ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin oníwà ipá Nítorí náà èmi ó fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa , láàrin àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ Òun ni ilé-ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀ ó sì fi àánú hàn fún ẹni-àmì-òróró rẹ̀, fún Dáfídì, àti fún irú-ọmọ rẹ̀ títí láéláé Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Dáfídì Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dáfídì Dáfídì ọmọ Jésè, àní ọkùnrin tí a ti gbéga, ẹni-àmì òróró Ọlọ́run Jákọ́bù, àti olórin dídùn Ísírẹ́lì wí pé Ẹ̀mí Olúwa sọ ọ̀rọ̀ nípa mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni, àpáta Ísírélì sọ fún mi pé Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run Yóò sì dà bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkúukùu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò Lóòtọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, tí a túnṣe nínú ohun gbogbo, tí a sì pamọ́ nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi, ilé mi kò lè ṣe kí ó má dágbà Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Bélíálì yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣátì, nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí yóò tọ́ wọn yóò fi irin àti ọ̀pá ọ̀kọ̀ ṣagbára yí ara rẹ̀ ká wọn ó Jóná lúúlú níbì kan náà Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọkùnrin alágbára tí Dáfídì ní Jósébù-básébè ti ará Takímónì ni olorí àwọn Balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Élíásárì ọmọ Dódò ará Áhóhì, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti wà pẹ̀lú Dáfídì, nígbà tí wọ́n pe àwọn Fílístínì ní ìjà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì ti lọ kúrò Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Fílístínì títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà Olúwa sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Sámímà ọmọ Ágè ará Hárárì, àwọn Fílístínì sì kó ara wọn jọ ní Léhì, oko kan tí ó kún fun ẹwẹ àwọn ènìyàn sì sá kúrò níwájú àwọn Fílístínì Òun sì dúró láàrin méjì ilẹ̀ náà, ó sì gbàá sílẹ̀, ó sì pa àwọn Fílístínì Olúwa sì ṣe ìgbàlà ńlá Àwọn mẹ́ta nínú ọgbọ̀n olórí sì sọkalẹ̀, wọ́n sì tọ Dáfídì wá ní àkókò ìkórè nínú ihò Ádúlámù ọ̀wọ́ àwọn Fílístínì sì dó sí àfonífojì Réfáímù Dáfídì sì wà nínú odi, ibùdó àwọn Fílístínì sì wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nígbà náà Dáfídì sì ń pòùngbẹ, ó wí bayìí pé, Ta ni yóò fún mi mu nínú omí kàǹga tí ń bẹ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu bodè Àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta sì la ogún àwọn Fílístínì lọ, wọ́n sì fa omi látinú kàǹga Bẹ́tílẹ́hẹ́mù wá, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu bodè, wọ́n sì mú tọ Dáfídì wá òun kò sì fẹ́ mu nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tú u sílẹ̀ fún Olúwa Òun sì wí pé, Kí a má rí, Olúwa , tí èmi ó fi ṣe èyí ṣé èyí ni ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tí ó lọ tí àwọn tí ẹ̀mí wọn lọ́wọ́ Nítorí náà òun kò sì fẹ́ mú un Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe Ábíṣáì, arákùnrin Jóábù, ọmọ Sérúíà, òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta Ọlọ́lá jùlọ ni òun jẹ́ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ó sì jẹ́ olórí fún wọn ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ìṣáájú Bénáyà, ọmọ Jéhóíádà, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabiseélì, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Áríélì méjì ti Móábù ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjòdídì Ó sì pa ará Éjíbítì kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò ará Éjíbítì náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n òun sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Éjíbítì náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á Nǹkan wọ̀nyí ní Banáyà ọmọ Jéhóíádà ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà Nínú àwọn ọgbọ̀n náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú Dáfídì sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀ Ásáhélì arákùnrin Jóábù sì Jásí ọ̀kan nínú àwọn ọgbọ̀n náà Élíhánánì ọmọ Dódò ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Ṣámà ará Háródì, Élíkà ará Háródì Hélésì ará Pálitì, Irá ọmọ Íkéṣì ará Tékóà Ábíésérì ará Ánétótì, Móbúnnáì Húṣátítì Sálímónì ará Áhóhì, Máháráì ará Nétófà Hélébù ọmọ Báánà, árá Nétófà, Íttaì ọmọ Ríbáì to Gíbéà ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì Bénáyà ará Pírátónì, Hídáyì tí àfonífojì Ábíálíbónì ará Áríbà, Ásámífétì Báríhúmítì Élíáhíbà ará Sáálíbónì, Jáṣénì Gísónítì, Jónátanì Ṣámà ará Hárárì, Áhíámù ọmọ Ṣárárì ará Hárárì Élífélétì ọmọ Áhásibáyì, ọmọ ará Máákíhà, Élíámù ọmọ Áhítófélì ará Gílónì Hésiráì ará Kérímélì, Páárì ará Áríbà Ígálì ọmọ Nátanì ti Sóbà, Bánì ará Gádì Sélékì ará Ámónì, Náhárì ará Béérótì, ẹni tí ń ru ìhámọ́ra Jóábù ọmọ Sérúíà Írà ará Játírì, Gárébù ará Játírì Ùráyà ará Hítì Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́tadínlógójì Kíka Àwọn Ènìyàn Ísírẹ́lì Ìbínú Olúwa sì ru sí Ísírẹ́lì, ó sì ti Dáfídì sí wọn, pé, Lọ ka iye Ísírẹ́lì àti Júdà! Ọba sì wí fún Jóábù Olórí ogun, tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, Lọ ní ìsinsìnyìí sí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti Dánì títí dé Bíásébà, kí ẹ sì ka iye àwọn ènìyàn, kí èmi lè mọ iye àwọn ènìyàn náà! Jóábù sì wí fún ọba pé, Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi kún ìye àwọn ènìyàn náà, ìyekíye kí ó wù kí wọn jẹ́, ní ọrọrún, ojú Olúwa mi ọba yóò sì rí i ṣùgbọ́n èétiṣe tí Olúwa mi ọba fi fẹ́ nǹkan yìí Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí ti Jóábù, àti ti àwọn olórí ogun Jóábù àti àwọn olórí ogun sì jáde lọ kúrò níwájú ọba, láti lọ ka àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì Wọ́n sì kọjá odò Jọ́dánì, wọ́n sì pàgọ́ ní Áróérì, ní ìhà apá ọtún ìlú tí ó wà láàrin àfonífojì Gádì, àti sí ìhà Jásérì Wọ́n sì wá sí Gílíádì, àti sí ilé Tátímhódíṣì wọ́n sì wá sí Dan-Jaanì àti yíkákiri sí Sídónì, Wọ́n sì wá sí ìlú olodi Tírè, àti sí gbogbo ìlú àwọn Hífì, àti ti àwọn ará Kénánì wọ́n sì jáde lọ síhà gúsù ti Júdà, àní sí Bééríṣébà Wọ́n sì la gbogbo ilẹ̀ náà já, wọ́n sì wá sí Jérúsálẹ́mù ní òpin oṣù kẹsàn-án àti ogúnjọ́ Jóábù sì fi iye tí àwọn ènìyàn náà jásí lé ọba lọ́wọ́ ó sì jẹ́ òjì ọ̀kẹ́ ọkùnrin alágbára ní Ísírẹ́lì, àwọn onídà àwọn ọkùnrin Júdà sì jẹ́ ọkẹ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ènìyàn Àyà Dáfídì sì gbọgbẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí ó ka àwọn ènìyàn náà tán Dáfídì sì wí fún Olúwa pé, Èmi ṣẹ̀ gidigidi ní èyí tí èmi ṣe ṣùgbọ́n, èmi bẹ̀ ọ, Olúwa , fi ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jìn ní, nítorí pé èmi hùwà aṣiwèrè gidigidi! Dáfídì sì dìde ní òwúrọ̀, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Gádì wòlíì wá, aríran Dáfídì wí pé Lọ kí o sì wí fún Dáfídì pé, Bàyìí ni Olúwa wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́ yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ   Gádì sì tọ Dáfídì wá, ó sì bi í léèrè pé, Kí ìyàn ọdún méje ó tọ̀ ọ́ wá ní ilẹ̀ rẹ bí Tàbí kí ìwọ máa sá ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀ta rẹ, nígbà tí wọn ó máa lé ọ Tàbí kí àrun ìparun ijọ́ mẹ́ta ó wá sí ilẹ̀ rẹ Ròó nísinsin yìí, kí o sì mọ èsì tí èmi ó mú padà tọ ẹni tí ó rán mi Dáfídì sì wí fún Gádì pé, Ìyọnu ńlá bá mi Jẹ́ kí a fi ara wa lé Olúwa lọ́wọ́ nítorí pé àánú rẹ̀ pọ̀ kí ó má sì ṣe fi mí lé ènìyàn lọ́wọ́ Olúwa sì rán àrùn ìparun sí Ísírẹ́lì láti òwúrọ̀ títí dé àkókò tí a dá ẹgbàá márùndínlógójì ènìyàn sì kú nínú àwọn ènìyàn náà láti Dánì títí fi dé Bééríṣébà Nígbà tí ańgẹ́lì náà sì nawọ́ rẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù láti pa á run, Olúwa sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì sọ fún ańgẹ́li tí ń pá àwọn ènìyàn náà run pé, Ó tó, dá ọwọ́ rẹ dúró wàyìí! Ańgẹ́lì Olúwa náà sì wà níbi ìpakà Áráúnà ará Jèbúsì Dáfídì sì wí fún Olúwa nígbà tí ó rí ańgẹ́li tí ń kọlu àwọn ènìyàn pé, Wò ó, èmi ti ṣẹ̀, èmi sì ti hùwà búburú ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí, kín ni wọ́n ha ṣe Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, kí ó wà lára mi àti ìdílé baba mi Gádì sì tọ Dáfídì wá lọ́jọ́ náà, ó sì wí fún un pé, Gòkè, tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa níbi ìpakà Áráúnà ará Jébúsì Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gádì, Dáfídì sì gòkè lọ bí Olúwa ti pa á láṣẹ Áráúnà sì wò, ó sì rí ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ wá lọ́dọ̀ rẹ̀ Áráúnà sì jáde, ó sì wólẹ̀ níwájú ọba ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀ Áráúnà sì wí pé, Nítorí kín ni Olúwa mi ọba ṣe tọ ìránṣẹ́ rẹ̀ wá Dáfídì sì dáhùn pé, Láti ra ibi ìpakà rẹ lọ́wọ́ rẹ, láti tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa , kí àrùn ìparun lè dá lára àwọn ènìyàn náà Áráúnà sì wí fún Dáfídì pé, Jẹ́ kí Olúwa mi ọba ó mú èyí tí ó dára lójú rẹ̀, kí o sì fi í rúbọ wò ó, màlúù nìyìí láti fi ṣe ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà, àti ohun èlò mìíràn ti màlúù fún igi Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Áráúnà fi fún ọba, bí ọba Áráúnà sì wí fún ọba pé, Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ ó gba ọrẹ rẹ Ọba sì wí fún Áráúnà pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́ ṣùgbọ́n èmi ó rà á ní iye kan lọ́wọ́ rẹ, bí ó ti wù kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi èyí tí èmi kò náwó fún, rú ẹbọ sísun sí Olúwa Ọlọ́run mi Dáfídì sì ra ibi ìpakà náà, àti àwọn màlúù náà ní àádọ́ta sékélì fàdákà Dáfídì sì tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ sí Olúwa , ó sì rú ẹbọ sísun àti ti ìlàjà Olúwa sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, àrùn náà sì dá kúrò ní Ísírẹ́lì Ábínérì àti Íṣíbóṣétì Jà Ogun náà sì pẹ́ títí láàrin ìdílé Ṣọ́ọ̀lù àti ìdílé Dáfídì agbára Dáfídì sì ń pọ̀ si i, ṣùgbọ́n ìdílé Ṣọ́ọ̀lù ń rẹ̀yìn si i Dáfídì sì bí ọmọkùnrin ní Hébírónì Ámónì ni àkọ́bí rẹ̀ tí Áhínóámù ará Jésírẹ́lì bí fún un Èkéjì rẹ̀ sì ni Kíléábù, tí Ábígáílì àya Nábálì ará Kárímẹ́lì bí fún un ẹ̀kẹta sì ni Ábúsálómù ọmọ tí Máákà ọmọbìnrin Tálímáì ọba Gésúrì bí fún un Ẹ̀kẹ́rin sì ni Àdóníjà ọmọ Hágítì àti ìkarún ni Séfátíà ọmọ Ábítalì Ẹ̀kẹfà sì ni Ítíréámù, tí Égílà àya Dáfídì bí fún un Wọ̀nyí ni a bí fún Dáfídì ni Hébúrónì Ó sì ṣe, nígbà tí ogun wà láàárin ìdílé Ṣọ́ọ̀lù àti ìdílé Dáfídì, Ábínérì sì dì alágbára ní ìdílé Ṣọ́ọ̀lù Ṣọ́ọ̀lù ti ní àlè kan, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Rísípà, ọmọbínrin Áíyà Íṣíbóṣétì sì bi Ábínérì léèrè pé, Èéṣe tí ìwọ fi wọlé tọ àlè baba mi lọ Ábínérì sì bínú gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti Iṣibósẹ́tì sọ fún un, ó sì wí pé, Èmi jẹ́ bí orí ajá ti Júdà bí Di òní yìí ni mọ ṣàáánú fún ìdílé Ṣọ́ọ̀lù bàbá rẹ, àti fún àwọn arákùnrin rẹ̀, àti fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí èmi kò sì fi ọ́ lé Dáfídì lọ́wọ́, ìwọ sì kà ẹ̀ṣẹ̀ sí mí lọ́rùn nítorí obìnrin yìí lóní Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe Ábínérì, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí Olúwa ti búra fún Dáfídì, bí èmi kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ fún un Láti mú ìjọba náà kúrò ní ìdílé Ṣọ́ọ̀lù, àti láti gbé ìtẹ́ Dáfídì kalẹ̀ lorí Ísírẹ́lì, àti lórí Júdà, láti Dánì títí ó fi dé Bíáṣébà! Òun kò sì lè dá Ábínérì lóhùn kan nítorí tí ó bẹ̀rù rẹ̀ Ábínérì sì rán àwọn oníṣẹ́ sí Dáfídì nítorí rẹ̀ wí pé, Ti ta ni ilẹ̀ náà ń ṣe Bá mi ṣe àdéhùn, èmi yóò si kó gbogbo Ísírẹ́lì tọ̀ ọ́ wá Òun sì wí pé, Ó dárá, èmi ó bá ọ ṣe àdéhùn ṣùgbọ́n ohun kan ni èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, èyí ni pé, ìwọ kì yóò rí ojú mi, àfi bí ìwọ bá kọ́ mú Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù wá, nígbà tí ìwọ bá wá, láti rí ojú mi Dáfídì sì rán àwọn ìránṣẹ sí Iṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù pé, Fi Míkálì obìnrin mi lé mi lọ́wọ́, ẹni tí èmi ti fi ọgọ́rún atoro àwọn Fílístínì fẹ́ Íṣíbóṣétì sì ránṣẹ́, ó sì gbà á lọ́wọ́ ọkùnrin tí a ń pè ní Fálítíélì ọmọ Láíṣì Ọkọ rẹ̀ sì ń bà a lọ, ó ń rìn, ó sì ń sunkún lẹ́yìn rẹ̀ títí ó fi dé Báhúrímù Ábínérì sì wí fún un pé, Padà sẹ́yìn! Òun sì padà Ábínérì sì bá àwọn àgbà Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ pé, Ẹ̀yin ti ń ṣe àfẹ́rí Dáfídì ní ìgbà àtijọ́, láti jọba lórí yín Ǹjẹ́, ẹ ṣe nítorí tí Olúwa ti sọ fún Dáfídì pé, Láti ọwọ́ Dáfídì ìránṣẹ mi lémi ó gba Isíraẹ́lì ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀taa wọn   Ábínérì sì sọ̀rọ̀ létí Béńjámẹ́nì Ábínérì sì lọ sọ létí Dáfídì ní Hébírónì, gbogbo èyí tí ó dára lójú Ísírẹ́lì, àti lójú gbogbo ilé Béńjámíní Ábínérì sì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, ogún ọmọkùnrin sì lọ pẹ̀lú rẹ̀ Dáfídì sì se àsè fún Ábínérì àti fún àwọn ọmọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ Ábínérì sì wí fún Dáfídì pé, Èmi ó dìde, èmi ó sì lọ, èmi ó sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ ọba Olúwa mi, wọn ó sì báa ṣe àdéhùn, ìwọ ó sì jọba gbogbo wọn bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́ Dáfídì sì rán Ábínérì lọ òun sì lọ ní àlàáfíà Sì wò ó, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì àti Jóábù sì ti ibi ìlépa ẹgbẹ́ ogun kan bọ̀, wọ́n sì mú ìkógún púpọ̀ bọ̀ ṣùgbọ́n Ábínérì kò sí lọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébírónì nítorí tí òun ti rán an lọ òun sì ti lọ ní Àlàáfíà Nígbà tí Jóábù àti gbogbo ogun tí ó pẹ̀lú rẹ̀ sì dé, wọ́n sì sọ fún Jóábù pé Ábínérì, ọmọ Nérì ti tọ ọba wá, òun sì ti rán an lọ, ó sì ti lọ ní àlàáfíà Jóábù sì tọ ọba wá, ó sì sọ pé, Kí ni ìwọ ṣe yìí Wò ó, Ábínérì tọ̀ ọ́ wá èé ha ti ṣe tí ìwọ sì fi rán an lọ Òun sì ti lọ Ìwọ mọ Ábínérì ọmọ Nérì, pé ó wá láti tàn ọ́ jẹ ni, àti láti mọ ìjáde lọ rẹ, àti wíwọlé rẹ́ àti láti mọ gbogbo èyí tí ìwọ ń ṣe Nígbà tí Jóábù sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ láti lépa Ábínérì, wọ́n sì pè é padà láti ibi kànga Sírà Dáfídì kò sì mọ̀ Ábínérì sì padà sí Hébírónì, Jóabù sì bá a tẹ̀ láàrin ojú ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà, ó sì gún un níbẹ̀ lábẹ́ inú, ó sì kú, nítorí ẹ̀jẹ̀ Ásáhẹ́lì arákùnrin rẹ̀ Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì sì gbọ́ ọ ó sì wí pé, Èmi àti ìjọba mi sì jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Olúwa títí láé ní ti ẹ̀jẹ̀ Ábínérì ọmọ Nérì Jẹ́ kí ó wà ní orí Jóabù, àti ní orí gbogbo ìdílé baba rẹ̀ kí a má sì fẹ́ ẹni ó tí ní àrùn ìṣun, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí ẹni tí ń tẹ ọ̀pá, tàbí ẹni tí a ó fi ìdà pa, tàbí ẹni tí ó ṣe aláìní oúnjẹ kù ní ilé Jóábù Dáfídì sì wí fún Jóábù àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ-ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yín sì sunkún níwájú Ábínérì Dáfídì ọba tìkararẹ̀ sì tẹ̀lẹ́ pósí rẹ̀ Wọ́n sì sin Ábínérì ní Hébírónì ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sunkùn ní ibojì Ábínérì gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sunkún Ọba sì sọkún lórí Ábínérì, ó sì wí pé, Ǹjẹ́ Ábínérì yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè A kò sáà dè ọ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀ Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dáfídì ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dáfídì sì búra wí pé, Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ ounjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí òòrùn yóò fi wọ̀! Gbogbo àwọn ènìyàn sì kíyèsí i, ó sì dára lójú wọn gbogbo èyí tí ọba ṣe sì dára lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà Gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo Ísírẹ́lì sì mọ̀ lọ́jọ́ náà pé, kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti pa Ábínérì ọmọ Nérì Ọba sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ̀yin kò mọ̀ pé olórí àti ẹni-ńlá kan ni ó ṣubú lónìí ní Ísírẹ́lì Èmi sì ṣe aláìlágbára lónìí, bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé a fi èmi jọba àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ọmọ Saerúíà sì le jù mí lọ Olúwa ni yóò san án fún ẹni tí ó ṣe ibi gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀! Ikú Íṣíbóṣétì Nígbà tí ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́ pé, Ábínérì kú ní Hébírónì, ọwọ́ rẹ̀ sì rọ, gbogbo Ísírẹ́lì sì rẹ̀wẹ̀sì Ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì ní ọkùnrin méjì tí í ṣe olórí ẹgbẹ́ ogun a ń pe orúkọ ọ̀kan ní Báánà, àti orúkọ ìkẹjì ní Rákábù, àwọn ọmọ Rímímónì ará Béérótì ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì Àwọn ará Béérótì sì ti sá lọ sí Gítaímù, wọ́n sì ṣe àtìpó níbẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ òní yìí Àwọn ọmọ Rímímónì, ará Béérótì, Rákábù àti Báánà sì lọ wọ́n sì wá sí ilé Iṣíbóṣétì ní ọsán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́ kan-rí Sì wò ó, bí Olùsọ́ ẹnú ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárin ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú àlìkámà Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sá lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà Wọ́n sì gbé orí Íṣíbóṣétì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, wọ́n sì wí fún ọba pé, Wò ó, orí Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù ọ̀ta rẹ, tí ó ti ń wá ẹ̀mí rẹ kíri, Olúwa ti gbẹ̀san fún ọba Olúwa mi lónìí lára Ṣọ́ọ̀lù àti lára irú-ọmọ rẹ̀ Dáfídì sì dá Rákábù àti Báánà arakùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Rímímónì ará Béérótì lóhùn, ó sì wí fún wọn pé, Bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ gbogbo ìpọ́njú Nígbà tí ẹnìkan rò fún mi pé, Wò ó, Ṣọ́ọ̀lù ti kú, lójú ara rẹ̀ òun sì jásí ẹni tí ó mú ìhìnrere wá, èmi sì mú un, mo sì pa á ní Síkílágì, ẹni tí ó ṣebí òun ó rí nǹkan gbà nítorí ìhìn rere rẹ̀ Mélòó mélòó ni, nígbà tí àwọn ìká ènìyàn pa olódodo ènìyàn kan ni ilé rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀—ǹjẹ́ èmi ha sì lè ṣe aláìbéèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yín bí Kí èmi sì mú yín kúrò láàyè Dáfídì sì fi àṣẹ fún àwọn ọdọ́mọkùnrin rẹ̀, wọ́n sì pa wọ́n, wọ́n sì gé ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn, a sì fi wọ́n há lórí igi ní Hébírónì Ṣùgbọ́n wọ́n mú orí Íṣíbóṣétì, wọ́n sì sin ín ní ibojì Ábínérì ní Hébírónì A fi Dáfídì Jọba Lórí Gbogbo Ísírẹ́lì Gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì sì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, wọ́n sì wí pé, Wò ó, egungun rẹ àti ẹran ara rẹ ni àwa ń ṣe Àti nígbà àtijọ́, nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù fi jọba lórí wa, ìwọ ni ẹni tí ó máa ń kó Ísírẹ́lì jáde, ìwọ sì ni ó máa ń mú wọn bọ̀ wá ilé Olúwa sì wí fún ọ pé, Ìwọ ó ṣe olùsọ́ Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn mi, ìwọ ó sì jẹ́ olórí fún Ísírẹ́lì   Gbogbo àgbà Ísírẹ́lì sì tọ ọba wá ní Hébírónì, Dáfídì ọba sì bá wọn ṣe àdéhùn kan ní Hébírónì, níwájú Olúwa wọ́n sì fi òróró yan Dáfídì ní ọba Ísírẹ́lì Dáfídì sì jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jọba ó sì jọba ní ogójì ọdún Ó jọba ní Hébírónì ní ọdún méje àti oṣù mẹ́fà lórí Júdà ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lórí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà Àti ọba àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Jérúsálẹ́mù sọ́dọ̀ àwọn ará Jébúsì, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àwọn tí ó sì ti wí fún Dáfídì pé, Bí kò ṣe pé ìwọ bá mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ́ kúrò, ìwọ kì yóò wọ ìhín wá wọ́n sì wí pé, Dáfídì kì yóò lè wá síhìn ín Ṣùgbọ́n Dáfídì fi agbára gba ìlú odì Síónì èyí náà ni í ṣe ìlú Dáfídì Dáfídì sọ lọ́jọ́ náà pé, Ẹnikẹ́ni tí yóò kọlu àwọn ará Jébúsì, jẹ́ kí ó gba ojú àgbàrá, kí o sí kọlu àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú tí ọkàn Dáfídì kórìíra Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí pé, Afọ́jú àti arọ wà níbẹ̀, kì yóò lè wọlé Dáfídì sì jókòó ní ilé àwọn ọmọ ogun tí ó ní odi, a sì ń pè é ní ìlú Dáfídì Dáfídì mọ ìgànná yí i ká láti Mílò wá, ó sì kọ́ ilé nínú rẹ̀ Dáfídì sì ń pọ̀ si i, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì wà pẹ̀lú rẹ̀ Hírámù ọba Tírè sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dáfídì, àti igi kédárì, àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn tí ń gbẹ́ òkúta, wọ́n kọ́ ilé kan fún Dáfídì Dáfídì sì kíyèsi i pé, Olúwa ti fi ìdí òun múlẹ̀ láti jọba lórí Ísírẹ́lì, àti pé, ó gbé ìjọba rẹ̀ ga nítorí Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀ Dáfídì sì tún mú àwọn àlè àti aya sí i láti Jérúsálẹ́mù wá, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti Hébírónì bọ̀ wọ́n sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin fún Dáfídì Èyí sì ni orúkọ àwọn tí a bí fún un ní Jérúsálẹ́mù Ṣamímúà àti Sóbábù, àti Nátanì, àti Sólómónì Àti Íbéhárì, àti Élíṣúà, àti Néfégì, àti Jáfíà Àti Élíṣámà, àti Élíádà, àti Élífélétì Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Fílístínì gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dáfídì jọba lórí Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn Fílístínì sì gòkè wá láti wá Dáfídì Dáfídì sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódì Àwọn Fílístínì sì wá, wọ́n sì tẹ ara wọn ní àfonífojì Réfáímù Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, Kí èmi ó gòkè tọ àwọn Fílístínì bí Ìwọ ó fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ bí Olúwa sì wí fún Dáfídì pé, Gòkè lọ, nítorí pé dájúdájú èmi ó fi àwọn Fílístínì lé ọ lọ́wọ́ Dáfídì sì dé Baal-Perasímù, Dáfídì sì pa wọ́n níbẹ̀, ó sì wí pé, Olúwa ti ya lu àwọn ọta mi níwájú mi, gẹ́gẹ́ bí omi ti ń ya Nítorí náà ni òun ṣe pe orúkọ ibẹ̀ náà ni Baal-Perasímù Wọ́n sì fi òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì kó wọn Àwọn Fílístínì sì tún gòkè wá, wọ́n sì tan ara wọn kalẹ̀ ní àfonífojì Rafaímù Dáfídì sì bèèrè lọ́dọ̀ Olúwa , òun sì wí pé, Má ṣe gòkè lọ ṣùgbọ́n bù wọ́n lẹ́yìn, kí o sì kọlù wọ́n níwájú àwọn igi Bákà Yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá gbọ́ ìró ẹṣẹ̀ lórí àwọn igi Bákà náà, nígbà náà ni ìwọ yóò sì yára, nítorí pé nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ níwájú rẹ láti kọlù ogun àwọn Fílístínì Dáfídì sì ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un ó sì kọlu àwọn Fílístínì láti Gébà títí dé Gásérì Ìrìnàjò Láti Gbé Àpótí-Ẹ̀rí- Dáfídì sì tún kó gbogbo àwọn akọni ọkùnrin ní Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún Dáfídì sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Báálà Júdà wá, láti mú àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrin àwọn kérúbù Wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Ábínádábù wá, èyí tí ó wà ní Gíbéà Úsà àti Áhíò, àwọn ọmọ Ábínádábù sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà Wọ́n sì mú un láti ilé Ábínádábù jáde wá, tí ó wà ní Gíbéà, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Áhíò sì ń rìn níwájú àpótí-ẹ̀rí náà Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì ṣiré níwájú Olúwa lára gbogbo onírúurúu èlò orin àti ìlù háàpù, ní ara tanborí, sisitirumù àti kíńbálì Nígbà tí wọ́n sì dé ibi ìpakà Nákónì, Úsà sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run, ó sì dì í mú, nítorí tí màlúù kọsẹ̀ Ibínú Olúwa sì ru sí Úsà Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣìṣe rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run Inú Dáfídì sì bàjẹ́ nítorí tí Olúwa gé Úsà kúrò ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Peresí-Úsà títí ó fi di òní yìí Dáfídì sì bẹ̀rù Olúwa ní ijọ́ náà, ó sì wí pé, Àpótí-ẹ̀rí Olúwa yóò ti ṣe tọ̀ mí wá Dáfídì kò sì fẹ́ mú àpótí-ẹ̀rí Olúwa sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dáfídì ṣùgbọ́n Dáfídì sì mú un yà sí ilé Obedì-Édómù ará Gátì Àpótí-ẹ̀rí Olúwa sì gbé ní ilé Obedì-Édómù ará Gátì ní oṣù mẹ́ta Olúwa sì bùkún fún Obedì-Édómù, àti gbogbo ilé rẹ̀ A sì rò fún Dáfídì ọba pé, Olúwa ti bùkún fún ilé Obedì-Édómù, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run Dáfídì sì lọ, ó sì mú àpótí-ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedì-Édómù wá sí ìlú Dáfídì pẹ̀lú ayọ̀ Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí-ẹ̀rí Olúwa bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rúbọ Dáfídì sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú Olúwa Dáfídì sì wọ éfódù ọ̀gbọ̀ Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè Bí àpótí-ẹ̀rí Olúwa sì ti wọ ìlú Dáfídì wá Mikali ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dáfídì ọba ń fò sòkè ó sì ń jó níwájú Olúwa òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀ Wọ́n sì mú àpótí-ẹ̀rí Olúwa náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrin àgọ́ náà tí Dáfídì pa fún un Dáfídì sì rubọ́ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú Olúwa Dáfídì sì parí ìṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó sì súre fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Ísírẹ́lì, àti ọkùnrin àti obìnrin fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti èkìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀ Dáfídì sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù sì jáde láti wá pàdé Dáfídì, ó sì wí pé, Báwo ni ọba Ísírẹ́lì ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀ Dáfídì sì wí fún Míkálì pé, Níwájú Olúwa ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn Olúwa , àní lórí Ísírẹ́lì, èmi ó sì ṣúre níwájú Olúwa Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìnìyín lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀ òdì yìí sí Dáfídì Dáfídì Fẹ́ Láti Kọ́ Tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run Ó sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí Olúwa sì fún un ní ìsinmi yíká kiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ Ọba sì wí fún Nátánì wòlíì pé, Sá wò ó èmi ń gbé inú ilẹ̀ tí a fi kédárì kọ́, ṣùgbọ́n àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run ń gbé inú ibi tí a fi aṣọ gé Nátanì sì wí fún ọba pé, Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Nátánì wá pé Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dáfídì, pé, Báyìí ni Olúwa wí Ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé Nítorí pé, èmi kò ì ti gbé inú ilé kan láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gòkè ti ilẹ̀ Éjíbítì wá, títí di òní yìí, ṣùgbọ́n èmi ti ń rìn nínú àgọ́, fún ibùgbé mi Ní ibi gbogbo tí èmi ti ń rìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ǹjẹ́ èmi ti bá ọ̀kan nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì, tí èmi pa àṣẹ fún láti máa bọ́ àwọn ènìyàn mi àní Ísírẹ́lì, sọ̀rọ̀ pé, Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi kédárì kọ́ ilé fún mi   Ǹjẹ́, nítorí náà, báyìí ni ìwọ yóò sì wí fún ìránṣẹ́ mi àní Dáfídì pé, Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi ti mú ìwọ kúrò láti inú agbo àgùntàn wá láti má tẹ̀lé àwọn àgùntàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì Èmi sì wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí ìwọ ń lọ, èmi sáà gé gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ kúrò níwájú rẹ, èmi sì ti sọ orúkọ rẹ di ńlá, gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá tí ó wà ní ayé Èmi ó sì yan ibìkan fún àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì, èmi ó sì gbìn wọ́n, wọn ó sì má gbé bí ibùjókòó ti wọn, wọn kì yóò sì ṣípò padà mọ́ àwọn ọmọ ènìyàn búburú kì yóò sì pọ́n wọn lójú mọ́, bí ìgbà àtijọ́ Àti gẹ́gẹ́ bí àkókò ìgbà tí èmi ti fi àṣẹ fún àwọn onídàájọ́ lórí àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì, èmi fi ìsinmi fún ọ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ   Olúwa sì wí fún ọ pé Olúwa yóò kọ ilé kan fún ọ Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ijọba rẹ kalẹ̀ Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé Èmi ó máa ṣe baba fún un, òun yóò sì máa jẹ́ ọmọ mi Bí òun bá dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì fi ọ̀pá ènìyàn nà án, àti ìnà àwọn ọmọ ènìyàn Ṣùgbọ́n àánú mi kì yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú un kúrò lọ́dọ̀ Ṣọ́ọ̀lù, tí èmi ti mú kúrò níwájú rẹ A ó sì fi ìdílé rẹ àti ìjọba rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ títí láé a ó sì fi ìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ títí láé   Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìran yìí, bẹ́ẹ̀ ni Nátanì sì sọ fún Dáfídì Dáfídì ọba sì wọlé lọ, ó sì dúró níwájú Olúwa , ó sì wí pé Olúwa Ọlọ́run, ta ni èmi, àti kí sì ni ìdílé mi, tí ìwọ fi mú mi di ìsinsin yìí Nǹkan kékeré ni èyí sáà jásí lójú rẹ, Olúwa Ọlọ́run ìwọ sì ti sọ nípa ìdílé ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú ní ti àkókò tí o jìnnà Èyí há ṣe ìwà ènìyàn bí, Olúwa Ọlọ́run Àti kín ní ó tún kù tí Dáfídì ìbá tún máa wí fún ọ Ìwọ, Olúwa Ọlọ́run mọ̀ ìránṣẹ́ rẹ Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni ìwọ ṣe ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí, kí ìránṣẹ́ rẹ lè mọ̀ Ìwọ sì tóbi, Olúwa Ọlọ́run kò sì sí ẹni tí ó dà bí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan lẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí àwa fi etí wá gbọ́ Orílẹ̀-èdè kan wo ni ó sì ń bẹ ní ayé tí ó dà bí àwọn ènìyàn rẹ, àní Ísírẹ́lì, àwọn tí Ọlọ́run lọ ràpadà láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ̀, àti láti sọ wọ́n ní orúkọ, àti láti ṣe nǹkan ńlá fún un yín, àti nǹkan ìyanu fún ilé rẹ̀, níwájú àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ ti rà padà fún ara rẹ láti Éjíbítì wá, àní àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn òrìṣà wọn Ìwọ sì fi ìdí àwọn ènìyàn rẹ, àní Ísírẹ́lì kalẹ̀ fún ara rẹ láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ títí láé ìwọ Olúwa sì wá di Ọlọ́run fún wọn Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tí ìwọ sọ ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àti ní ti ìdílé rẹ̀, kí ó dúró títí láé, kí ó sí ṣe bí ìwọ ti wí Jẹ́ kí orúkọ rẹ ó ga títí láé, pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run lórí Ísírẹ́lì! Sì jẹ́ kí a fi ìdílé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ Nítorí pé ìwọ, Olúwa àwọn ọmọ-ogún, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti sọ létí ìránṣẹ́ rẹ, pé, Èmí ó kọ́ ilé kan fún ọ Nítorí náà ni ìránṣẹ́ rẹ sì ṣe ní i lọ́kàn rẹ̀ láti gbàdúrà yìí sí ọ Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run náà, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ sì jásí òtítọ́, ìwọ sì jẹ́ jèẹ́ nǹkan rere yìí fún ìránṣẹ́ rẹ Ǹjẹ́, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bùkún ìdílé ìránṣẹ rẹ, kí ó wà títí láé níwájú rẹ nítorí ìwọ, Olúwa Ọlọ́run, ni ó ti sọ ọ́ sì jẹ́ kí ìbùkún wà ní ìdílé ìránṣẹ́ rẹ títí láé, nípaṣẹ̀ ìbùkún rẹ Dáfídì Ń Ti Ìsẹgun Dé Ìṣégun Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Dáfídì sì kọlu àwọn Fílístínì, ó sì tẹrí wọn ba Dáfídì sì gba Metegamímà lọ́wọ́ àwọn Fílístínì Ó sì kọlu Móábù, ó sì fi okùn títa kan dìwọ́n, ó sì dá wọn dùbúlẹ̀ ó sì ṣe òṣùwọ̀n okùn méjì ni iye àwọn tí yóò dá sí Àwọn ará Móábù sì ń sin Dáfídì, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá Dáfídì sì kọlu Hadadésérì ọmọ Rehóbù, ọba Sóbà, bí òun sì ti ń lọ láti mú agbára rẹ̀ bọ̀ sípò ni odò Éfúrétì Dáfídì sì gba ẹgbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àti ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rin ẹlẹ́ṣin, àti ẹgbàawá àwọn ẹlẹ́sẹ̀ Dáfídì sì já gbogbo àwọn ẹṣin kẹ̀kẹ́ wọn ní pátì, ṣùgbọ́n ó dá ọgọ́rún kẹ̀kẹ́ sí nínú wọn Nígbà tí àwọn ará Síríà ti Dámásíkù sì wá láti ran Hadadésérì ọba Sóbà lọ́wọ́, Dáfídì sì pa ẹgbàámọ́kànlá ènìyàn nínú àwọn ará Síríà Dáfídì sì fi àwọn ológún sí Síríà ti Dámásíkù àwọn ará Síríà sì wá sin Dáfídì, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá, Olúwa sì pa Dáfídì mọ́ níbikíbi tí o ń lọ Dáfídì sì gba àṣà wúrà tí ó wà lára àwọn ìránṣẹ Hadadésérì, ó sì kó wọn wá sí Jérúsálẹ́mù Láti Bétà, àti láti Bérótáì, àwọn ìlú Hadadésérì, ni Dáfídì ọba sì kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ baba wá Nígbà tí Tóù ọba Hámátì sì gbọ́ pé Dáfídì ti pa gbogbo ogun Hadadésérì Tóì sì rán Jórámù ọmọ rẹ̀ sí Dáfídì ọba, láti kí i, àti láti súre fún un, nítorí pé ó tí bá Hadadésérì jagun, ó sì ti pa á nítorí tí Hadadésérì sáà ti bá Tóù jagun Jórámù sì ni ohun èlò fàdákà, àti ohun èlò wúrà, àti ohun èlò idẹ ní ọwọ́ rẹ̀ Dáfídì ọba sì fi wọ́n fún Olúwa pẹ̀lú fàdákà, àti wúrà tí ó yà sí mímọ́, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ àwọn orilẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹ́gun Lọ́wọ́ Síría àti lọ́wọ́ Móábù àti lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ámónì, àti lọ́wọ́ àwọn Fílístínì, àti lọ́wọ́ Ámálékì, àti nínú ìkógun Hadadésérì ọmọ Réhóbù ọba Sóbà Dáfídì sì ní òkìkí gidigidi nígbà tí ó padà wá ilé láti ibi pípa àwọn ará Síríà ní àfonífojì iyọ̀, àwọn tí o pa jẹ́ ẹgbaàsán ènìyàn Ó sì fi àwọn ológun sí Édómù àti ní gbogbo Édómù yíká ni òun sì fi ológun sí, gbogbo àwọn tí ó wà ní Édómù sì wá sin Dáfídì, Olúwa sì fún Dáfídì ní ìṣẹgún níbikíbi tí ó ń lọ Dáfídì sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì Dáfídì sì ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ Jóábù ọmọ Sérúyà ni ó sì ń ṣe olórí ogun Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì sì ń ṣe akọ̀wé Sádókù ọmọ Áhítúbì, àti Áhímélékì ọmọ Ábíátarì, ni àwọn àlùfáà Sérúyà a sì máa ṣe akọ̀wé Bénáyà ọmọ Jéhóíádà ni ó sì ń ṣe olórí àwọn Kérétì, àti àwọn Pélétì àwọn ọmọ Dáfídì sì jẹ́ aláṣẹ Dáfídì Ṣe Oore Fún Mẹ̀fíbósẹ́tì ọmọ Jónátanì Dáfídì sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Ṣọ́ọ̀lù kù síbẹ̀ bí Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jónátanì Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Ṣọ́ọ̀lù, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Síbà, Wọ́n sì pèé wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Ìwọ ni Síbà bí Ó sì dáhùn wí pé, Ìránṣẹ́ rẹ ni Ọba sì wí pé, Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Ṣọ́ọ̀lù ṣíbẹ̀, kí èmi ṣe ooré Ọlọ́run fún un Ṣíbà sì wí fún ọba pé, Jónátanì ní ọmọ kan ṣíbẹ̀ tó ya arọ Ọba sì wí fún un pé, Níbo ni ó gbé wà Síbà sì wí fún ọba pé, Wò ó, òun wà ní ilé Mákírì, ọmọ Ámíélì, ní Lódébárì Dáfídì ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Mákírì ọmọ Ámíélì láti Lódébárì wá Méfibóṣétì ọmọ Jónátaanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì tọ Dáfídì wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un Dáfídì sì wí pé, Méfibóṣétì! Òun sì dáhún wí pé, Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ! Dáfídì sì wí fún un pé, Má ṣe bẹ̀rù nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jónátanì baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Ṣọ́ọ̀lù baba rẹ fún ọ ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi Òun sì tẹríba, ó sì wí pé, Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jásí, tí ìwọ ó fi máa wo òkú ajá bí èmi Ọba sì pe Síbà ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù, ó sì wí fún un pé, Gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Ṣọ́ọ̀lù, àti gbogbo èyí tí í ṣe ti ìdílé rẹ̀ ni èmi fi fún ọmọ olúwa rẹ Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ró ilé náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkóre wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí òunjẹ jẹ ṣùgbọ́n Méfibóṣétì ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi Ṣíbà sì wí fún ọba pé, Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa mi ọba ti pa láṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe Ọba sì wí pé, Ní ti Méfibóṣétì, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba Méfibóṣétì sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Síbà ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Méfibóṣétì Méfibóṣétì sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ́ ọba òun sì yarọ ní ẹṣẹ̀ rẹ̀ méjèèjì Àdúrà Àti Ìdúpẹ́ Pọ́ọ̀lù, Sílà àti Tímótíù, Sí ìjọ Tẹsalóníkà, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jésù Kírísítì Olúwa Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jésù Kírísítì Olúwa Ó yẹ kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nítorí yín, ará, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà gidigidi, àti ìfẹ́ olúkúlùkù yín gbogbo sí ara yín ń di púpọ̀ Nítorí náà, àwa tìkara wa ń fi yín ṣògo nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà nínú gbogbo ìjọ Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé ní torí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà Olódodo ni Ọlọ́run Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú, Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú Èyí yóò sì se nígbà ìfarahàn Jésù Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì alágbára Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìyìn rere Jésù Olúwa wa A ó fi ìparun àìnípẹ̀kun jẹ wọ́n níyà, a ó sì se wọn mọ̀ kúrò níwájú Olúwa àti inú ògo agbára rẹ̀ Ní ọjọ́ tí yóò jẹ́ ẹni tí a ó yìn lógo nínú àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àti ẹni àwòyanu ní àárin gbogbo àwọn tí ó ti gbàgbọ́ Èyí kò yọ yín sílẹ̀, nítorí ẹ ti gba ẹ̀rí tí a jẹ́ sí yín gbọ́ Nítorí èyí, àwa pẹ̀lú ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọ́run wa kí ó lè kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀, àti pé nípa agbára rẹ̀, òun yóò mú gbogbo èrò rere yín sẹ àti gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ bá rú jáde Wọ̀nyí ni àdúrà wa, kí orúkọ Jésù Olúwa wa lè di yíyìn lógo nínú yín àti ẹ̀yin nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ti Jésù Kírísítì Olúwa Ọkùnrin Aláìlófin Náà Ní ti bíbọ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa, àti ti ìpéjọ wa sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa wí fún yín ará, kí ọkàn yín má ṣe àìbalẹ̀, tàbí kí ẹ má ṣe jáyà nípa àṣọtẹ́lẹ̀, ìròyìn tàbí lẹ́tà tí ó lè farajọ èyí tí ó le wá láti ọ̀dọ̀ wa, tí yóò máa wí pé ọjọ́ Olúwa ti dé ná Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó tàn yín jẹ ní ọ̀nàkọnà, nítorí pé ọjọ́ náà kì yóò dé, bí kò ṣe pé ìṣọ̀tẹ̀ bá kọ́ ṣẹlẹ̀, tí a sì fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, tí í ṣe ọmọ ègbé Òun yóò lòdì sí, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga sí gbogbo ohun tí a ń pè ní Ọlọ́run tàbí tí a ń sìn, dé ibi pé yóò gbé ara rẹ̀ jókòó nínú tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run, tí yóò sì ń pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run Ṣé ẹ̀yin kò rántí pé nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín, mo ń sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún-un yín Àti pé nísinyìí, ẹ̀yín mọ ohun tí ń dá a dúró, kí a bá a lè fi í hàn ní àkókò rẹ̀ gan an Nítorí agbára ìkọ̀kọ̀ ẹni ẹ̀ṣẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ń dènà yóò máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí a ó fi mú-un kúrò ní ọ̀nà Nígbà náà ni a ó fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, ẹni tí Jésù Olúwa yóò fi èémí ẹnu rẹ̀ pa, tí yóò sì fi ọlá ìpadàbọ̀ rẹ̀ parun Wíwá ẹni ẹ̀ṣẹ̀ yóò rí bí iṣẹ́ Sàtánì, gbogbo èyí tí a fihàn gẹ́gẹ́ bí àdàmọ̀dì iṣẹ́-ìyanu, àdàmọ̀dì àmì àti àdàmọ̀dì idán, Ní gbogbo ọ̀nà búburú tí a fi ń tan àwọn tí ń ṣègbé jẹ Wọ́n ṣègbé nítorí wọ́n kọ̀ láti fẹ́ràn òtítọ́ kí wọn sì di ẹni ìgbàlà Nítorí ìdí èyí, Ọlọ́run rán ohun tó ń ṣiṣẹ́ ìsìnà sí wọn kí wọn lè gba èké gbọ́, Kí wọn kí ó lè gba ìdálẹ́bi, àní àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ní inú-dídùn nínú ìwà-búburú Ṣùgbọ́n, ohun tí ó tọ́ fún wa ni láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará olùfẹ́ ní ti Olúwa, nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín sí ìgbàlà nípa ìṣọdi-mímọ́ ti Ẹ̀mí àti nípa gbígba òtítọ́ gbọ́ Òun ti pè yín sí èyí nípa ìyìn rere wa, kí ẹ̀yin kí ó lè pín nínú ògo Jésù Kírísítì Olúwa wa Nítorí náà ará, ẹ dúró sinsin, kí ẹ sì di àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a kọ́ yín mú, yálà nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí lẹ́tà Ǹjẹ́ kí Jésù Kírísítì Olúwa wa tìkalára rẹ̀, àti Ọlọ́run baba wa, ẹni to ti fẹ́ wa, tí ó sì ti fi ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́ fún wa Kí ó mú ọkàn yín le, kí ó sì kún yín pẹ̀lú agbára nínú iṣẹ́ gbogbo àti ọ̀rọ̀ rere gbogbo Ìtọrọ Àdúrà Ní àkótan, ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa, kí ọ̀rọ̀ Olúwa lè máa tàn káàkiri, kí ó sì jẹ́ èyí tí a bu ọlá fún, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀dọ̀ yín Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún wa kí a lè bọ lọ́wọ́ àwọn ìkà àti àwọn ènìyàn búburú, nítorí pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ní ìgbàgbọ́ Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi Àwa sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ní ti ohun tí ẹ ń ṣe, àti pé àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a pa láṣẹ fún-un yín ni ẹ̀yin ń ṣe Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín sọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kírísítì Ní orúkọ Jésù Kirisítì Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún-un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa farawé wa Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́ Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣisẹ́ tọ̀sán-tòru kí a má baà di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti bèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé Nítorí nígbà tí àwà wà lọ́dọ̀ yín, a ṣe àwọn òfin wọ̀nyí fún-un yín pé, Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun A gbọ́ pé àwọn kan wà láàrin yín tí wọn jẹ́ ìmẹ́lẹ́ Wọ́n jẹ́ ìmẹ́lẹ́ Wọ́n jẹ́ atọjúlé-kiri Ǹjẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa ń pàṣẹ́ fún, tí a sì ń rọ̀ nínú Jésù Kírísítì Olúwa pé kí wọn ó máa ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ Ṣùgbọ́n ní tiyín ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí agara dá yín ní rere síṣe Bí ẹnikẹ́ni kò bá sì pa ofin wa nínú lẹ́tà yìí mọ́, ẹ ṣààmí sí ẹni náà Ẹ má ṣe bá a kẹ́gbẹ́ kí ojú bà á le tì í Ṣíbẹ̀, ẹ má ṣe kà á sí ọ̀ta, ṣùgbọ́n ẹ máa kìlọ̀ fún-un gẹ́gẹ́ bí arakùnrin yín Ǹjẹ́ kí Olúwa àlàáfíà, fúnrarẹ̀ máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo Kí Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín Èmi Pọ́ọ̀lù fi ọwọ́ ara mi kọ lẹ́tà ìkíni yìí, èyí ṣe àmì ìdámọ̀ nínú gbogbo lẹ́tà Bí mo ṣe máa ń kọ̀wé nìyìí Kí oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa wà pẹ̀lú yín Ọ̀rọ̀ Ìkínní Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì ti Jésù Kírísítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè ti ń bẹ nínú Kírísítì Jésù Sí Tímótíù, Ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kírísítì Jésù Olúwa wa, Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí èmi ń sìn pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn funfun gẹ́gẹ́ bí àwọn baba mi ti í ṣe, pé ni àìsinmi lọ́sàn-án àti lóru ni mo ń ṣe ìrántí rẹ nínú àdúrà mi Bí mo ti rántí omijé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni mo ń fẹ́ láti rí ọ kí èmi kí ó lè kún fún ayọ̀ Nígbà ti mo bá rántí ìgbàgbọ́ àìlẹ́tàn rẹ, èyí ti ó kọ́kọ́ ń bẹ nínú Loisi ìyá-ńlá rẹ, àti nínú Yùníìsì ìyá rẹ̀ àti, èyí tí ó da mi lójú pé ó ń gbé inú rẹ̀ pẹ̀lú Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń ran ọ létí pé kí ó máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run sókè èyí ti ń bẹ nínú rẹ nípa ìgbọ́wọ́lé mi Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìṣẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ̀rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀ ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábàápín nínú ìpọ́njú ìyìnrere nípa agbára Ọlọ́run, ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà-mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa láti ìpìlẹ̀ ayérayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn níṣinṣinyìí nípa ìfarahàn Jésù Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípaṣẹ̀ ìyìnrere Fún ti ìyìnrere tí a yàn mi ṣe oníwàásù àti Àpósítélì àti olùkọ́ Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kírísítì Jésù Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa Èyí ni ìwọ mọ̀ pé, gbogbo àwọn ti ó wà ni agbègbè Ésíà ti fí mí sílẹ̀, nínú àwọn ẹni tí Fígélíù àti Hámógénè gbé wà Kí Olúwa fi àánú fún ilé Ònésífórù nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà ni Rómù, ó fi ẹ̀sọ̀ wá mi, ó sì rí mi Kí Olúwa fi fún un kí ó lè rí àánú lọ́dọ̀ Olúwa ni ọjọ́ náà! Ìwọ tìkararẹ sáà mọ̀ ọ̀nà gbogbo tí ó gbà rànmí lọ́wọ́ ni Éfésù Òṣìṣẹ́ Tí Ọlọ́run Yàn NÍTORÍ náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kírísítì Jésù Àwọn ohun ti ìwọ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn náà ni kí ìwọ fi lé àwọn olóòótọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àwọn ti yóò lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú Ṣe alábàápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jésù Kírísítì Kò sí ẹni tí ń jagun ti ń fi ohun ayé yìí dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè mú inú ẹni tí ó yàn ni ọmọ-ogun dùn Ní ọ̀nà kán náà, bí ẹnìkẹ́ni bá sì ń dije bí olùdíje, a kì í dé e ládé, bí kò ṣe bí ó bá parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Àgbẹ̀ ti ó ń ṣe làálàá ni ó yẹ láti kọ́kọ́ mu nínú àwọn èso Ronú lórí ohun ti èmi ń sọ nítorí Olúwa yóò fún ọ lóye nínú ohun gbogbo Rántí Jésù Kírísítì, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere mi Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́ kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù pẹ̀lú ògo ayérayé Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà Bi àwa bá bá a kú, àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀ Bí àwa bá faradà, àwa ó sì bá a jọba Bí àwa bá sẹ́ ẹ, òun náà yóò sì sẹ́ wa Bí àwa kò bá gbàgbọ́, òun dúró ni olóòótọ́ Nítorí òun kò lè sẹ ara rẹ̀ Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí Máa kìlọ̀ò fún wọn níwajú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́ Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò níláti tijú, tí ó ń pin ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ Yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán, nítorí ti wọn máa ṣíwájú nínú àìwà-bí-Ọlọ́run Ọ̀rọ̀ wọn yóò sì máa fẹ́ bí egbò kíkẹ̀ nínú àwọn ẹni tí Híménéù àti Fílétù wà Àwọn ẹni tí ó ti sìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ń wí pé àjíǹde ti kọjá ná tí wọ́n sì ń bi ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn ṣubú Ṣùgbọ́n ìpìlẹ̀ Ọlọ́run tí ó dájú dúró ṣinṣin, ó ní èdìdì yìí, pé, Olúwa mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀ Àti pẹ̀lú, Kí olúkúlùkù ẹni tí ń pé orúkọ Olúwa kúró nínú àìṣòdodo Ṣùgbọ́n nínú ilé nla, kì í ṣe kìkì ohun-èlò wúrà àti ti fàdákà nìkan ni ń bẹ, ṣùgbọ́n ti igi àti amọ̀ pẹ̀lú àti òmíràn sí ọlá, àti òmíràn sí àìlọ́lá Bí ẹnìkẹni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìwọ̀nyí, òun yóò jẹ́ ohun-èlò sí ọlá, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó sì yẹ fún ìlò baálé, tí a sì ti pèsè sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere gbogbo Máa sá fún ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ èwe sì máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn funfun wá Ìbéèrè òmùgọ̀ àti aláìní èkọ́ nínú ni kí a kọ̀, bí a ti mọ̀ pe wọn a máa dá ìjà sílẹ̀ Ìránsẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, onísùúrù Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrèti pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtìtọ́, wọn ó sì lè bọ́ kúrò nínú ìdèkùn èṣù, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti mú wọn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ Àìwùwà Bí Ọlọ́run Ni Ọjọ́ Ìkẹ̀yìn Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀ pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé Nitori àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀-búburú, aṣàìgbọ́ràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́ Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlè-dáríjí-ni, abanijẹ́, aláìlè-kó-rawọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwá-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀ yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ fà kiri Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́ Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Jánésì àti Jámbérì ti kọ ojú ìjà sí òtítọ́ àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́ Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ ṣíwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ Nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́-ni sùúrù Inúnibíni, ìyà àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Ańtíókù, Ní Ìkóníónì àti ní Lísítírà àwọn inúnibíni tí mo faradà Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kírísítì Jésù yóò faradà inúnibíni Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ̀tàn yóò máa burú síwajú sí i, wọn ó máa tan-nijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ ìwé-Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ́ ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Jésù Gbogbo ìwé-Mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo Kí ènìyàn Ọlọ́run lè pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fun iṣẹ́ rere gbogbo Àwọn Àkíyèsí Ti Ara Ẹni Nítorí náà mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kírísítì Jésù, ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀ Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsinmi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀ bániwí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó oluko jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kùfẹ́ ara wọn Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́nju, ṣe iṣẹ́ ẹ̀fáńjẹ́lísítì, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé Nitorí à ń fí mi rúbọ nisínsinyìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etíle Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́ Láti ìsinsinyìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàjọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀ Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá Nítorí Démà ti kọ̀ mí sílẹ̀, nitorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalóníkà Kírésíkénì sí Gálátíà, Títù sí Dalimátíà Lúùkù nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Máàkù wá pẹ̀lú rẹ nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́-ìránṣẹ́ Mo rán Tíkíkù ní iṣẹ lọ sí Éfésù Aṣọ òtútù tí mọ fi sílẹ̀ ní Tíróà lọ́dọ̀ Kárípù, nígbà tí ìwọ bá ń bọ̀ mu un wa, àti àwọn ìwé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìwé-awọ Alekisáńdérù alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mi ni ibi púpọ̀ Olúwa yóò san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ Lọ́dọ̀ ẹni tí kí ìwọ máa ṣọ́ra pẹ̀lú, nítorí tí ó kọ ojú ìjà sí ìwàásù wa púpọ̀ Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀ Àdúrà mi ni kí a má ṣe ká à sí wọn lọ́rùn Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára pé nipasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́ a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnìún náà Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ bubúrú gbogbo, yóò sì gbà mí dé inú ìjọba rẹ̀ ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé Kí Parísíkà àti Àkúílà, àti ilé Onésífórù Érásítù wà ní Kọ́ríntí ṣùgbọ́n mo fi Tírófímù sílẹ̀ ni Mílétù nínú àìsàn Sa ipá rẹ láti tètè wá ṣáájú ìgbà òtútù Éúbúlù kí ọ, àti Páúdánì, àti Línù, Kíláúdíà, àti gbogbo àwọn ará-kùnrin Kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú yín Alàgbà, Sì Gáyúsì, olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ nínú òtítọ́ Olùfẹ́, èmi ń gbàdúrà pé nínú ohun gbogbo kí o lè máa dára fún ọ, kí o sì máa wà ni ìlera, àní bí o tí dára fún ọkàn rẹ Nítorí mo yọ̀ gidigidi, nígbà tí àwọn arákùnrin dé tí wọn sì jẹ̀rìí sí ìwà òtítọ́ inú rẹ̀, àní bí ìwọ tí ń rìn nínú òtítọ́ Èmi ni ayọ̀ tí ó ó tayọ, láti máa gbọ́ pé, àwọn ọmọ mi ń rìn nínú ọ̀títọ́ Olùfẹ́, ìwọ ń ṣe olóòótọ́ nínú iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún àwọn tí ń ṣe ará, àti pàápàá fún àwọn tí ń ṣe àlejò Tí wọn ń jẹ̀rìí sí ìfẹ́ rẹ̀ níwájú ìjọ bí ìwọ bá ń pèsè fún wọ́n ní ọ̀nà àjò wọn gẹ́gẹ́ bí o tí yẹ nínú Ọlọ́run Nítorí pé nítorí iṣẹ́ Kírísítì ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgbà ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà Nítorí náà, ó yẹ kí àwa fi inú rere gba irú àwọn wọ̀nyí, kí àwa lè jẹ́ alábáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú òtítọ́ Èmi kọ̀wé sí ìjọ ṣùgbọ́n Díótíréfè, ẹni tí ó fẹ́ láti jẹ́ ẹni pàtàkì jùlọ, kò gbà wá Nítorí náà bí mo bá dé, èmi yóò mú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣe wá sì ìrántí rẹ, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ búburú àti ìsọkúsọ sí wa èyí kò sì tún tẹ́ ẹ lọ́rùn, síbẹ̀ òun fúnra rẹ̀ kọ̀ láti gba àwọn ará, àwọn tí o sì ń fẹ́ gbà wọn, ó ń dá wọn lẹ́kun, ó sì ń lé wọn kúrò nínú ìjọ Olùfẹ́, má ṣe ṣe àfarawé ohun tí í ṣe ibi bí kò ṣe ohun tí ṣe rere Ẹni tí ó bá ń ṣe rere ti Ọlọ́run ni ẹni tí ó ba ń ṣe búburú kò rí Ọlọ́run Démétírósì ní ẹ̀rí rere lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn àti ní ti òtítọ́ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú nítòótọ́, àwa pẹ̀lú sì gba ẹ̀rí rẹ̀ jẹ́ ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí wa Èmí ní ohun púpọ̀ láti kọ sínú ìwé sí ọ, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ kọ wọ́n sínú ìwé Mo ni ìrètí láti rí ọ láìpẹ́, tí àwa yóò sì sọ̀rọ̀ lójúkojú Àlàáfíà fún ọ Àwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà níbí kí ọ Kí àwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà níbẹ̀ yẹn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan A Mú Jésù Lọ Sí Ọ̀run Nínú ìwé mi ìṣáájú, Tèófilọ́sì, ni mo ti kọ ní ti ohun gbogbo tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àti kọ́ Títí ó fi di ọjọ́ tí a gbà á lọ sókè ọ̀run, lẹ́yìn tí ó ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn àpósítélì tí ó yàn Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láàyè Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run Nígbà kan, bí ó sì ti ń jẹun pẹ̀lú wọn, ó pàṣẹ yìí fún wọn Ẹ má ṣe kúrò ní Jerúsálémù, ṣùgbọ́n ẹ dúró de ẹ̀bùn tí Baba mi se ìlérí, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ lẹ́nu mi Nítorí Jòhánù fi omi bamitíìsì yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì yín Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọ pọ̀, wọn bi í léèrè pé, Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Ísírẹ́lì bí Ó sì wí fún wọn pé, Kì í ṣe ti yín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkárarẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerúsálémù, àti ní gbogbo Jùdíà, àti ní Samaríà, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, a gbà á sókè lójú wọn ìkùùkuu àwọsánmọ̀ sì gbà á kúrò lójú wọn Bí wọ́n sì ti tẹjúmọ́ ojú ọ̀run bí ó ti ń lọ sókè, lójijì, àwọn ọkùnrin méjì tí ó wọ aṣọ funfun dúró létí ọ̀dọ̀ wọn Wọ́n sì wí pé, Ẹ̀yin ara Gálílì, è é ṣe tí ẹ̀yin fi dúró tí ẹ̀ ń wo ojú ọ̀run Jésù yìí, tí a gbà sókè ọ̀run kúrò lọ́wọ́ yín, yóò padà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí tí ó ń lọ sì ọ̀run Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jerúsálému láti orí òkè ti a ń pè ni Ólífì, tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí ìyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé Àwọn tó wà níbẹ̀ ni Pétérù, àti Jákọ́bù àti Jòhánù, àti Áńdérù, àti Fílípì, àti Tọ́másì, Bátóléméù, àti Mátíù, Jákọ́bù ọmọ Álíféù, àti Símónì Sélótì, àti Júdà arakùnrin Jákọ́bù Gbogbo àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn obìnrin àti Màríà ìyá Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ọkàn kan dúró láti máa gbàdúrà Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni Pétérù sí díde dúró láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ó w í pé, Ẹ̀yin ará, ìwé-Mímọ́ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ, èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu Dáfídì nípa Júdásì, tí ó ṣe atọ́nà fún àwọn tí ó mú Jésù nítorí ọ̀kan nínú wa ni òun ń se tẹ́lẹ̀, òun sì ní ìpín nínú iṣẹ́-ìránṣẹ́ yìí Pétérù sì wí pé, Nítorí a ti kọ ọ́ nípa rẹ̀ pé nínú Ìwé Ṣáàmù pé,  Jẹ́ ki ibùjókòó rẹ̀ di ahoro, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀, àti, ipò rẹ̀ ni kí ẹlòmíràn kí ó gbà Nítorí náà, ó di dandan láti yan ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọn tí wọn ti ń bá wa rìn ni gbogbo àkókò tí Jésù Olúwa ń wọlé, tí ó sì jáde láàrin wa Bẹ́ẹ̀ láti ìgbà bamitíìsì Jòhánù títí ó fi di ọjọ́ náà ti a gbe é lọ sókè kúrò lọ́dọ̀ wa ó yẹ kí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa Wọn sì yan àwọn méjì, Jósẹ́fù tí a ń pè ní Básábà, àti Màtíà Wọn sì gbàdúrà, wọn sì wí pé, Olúwa, ìwọ mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, fihàn wá nínú àwọn méjì yìí, èwo ni ìwọ yàn kí ó lè gba ipò nínú iṣẹ́-ìránṣẹ́ àpósítélì yìí, èyí tí Júdásì kúrò nínú rẹ̀, ki òun kí ó lè lọ sí ipò ti ara rẹ̀ Wọ́n sì dìbò fún wọn ibò sí mú Mátíà a sì kà á mọ́ àwọn àpósitélì mọ́kànlá Àwọn Ìpè Kọ̀nélíù Fún Pétérù Ọkùnrin kan sì wà ni Kesaríà ti a ń pè ní Kọ̀nélíù, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Ítálì Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilé tilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo Níwọ̀n wákàtí kẹ́sàn-án ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere ańgẹ́lì Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, Kọ̀nélíù! Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, Kí ni, Olúwa Ó sì wí fún un pé, Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ ṣíwájú Ọlọ́run fún ìrántí Sì rán ènìyàn nísinsìnyìí lọ sí Jópà, kí wọn sì pe Símónì wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Pétérù Ó wọ̀ sí ilé Símónì aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí òkun òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe Nígbà tí ańgẹ́lì náà tí ó bá Kọ̀nélíù sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, ati ọmọ ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Jópà A fi ran hàn Pétérù pẹ̀lú Ni ijọ́ kéjì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Pétérù gun òkè ilé lọ gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́ Ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun ó bọ́ sí ojúran Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun-èlò kan si sọ̀kálẹ̀ bí gọ̀gọ̀wú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀ Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹrankọ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin wà, ati ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, Dìde, Pétérù máa pa kí o sì má a jẹ Ṣùgbọn Pétérù dáhùn pé, Àgbẹdọ̀, Olúwa nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ ati aláìmọ́ kan rí Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ́méjì pé, Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀ nù, ìwọ má ṣe pè é léèwọ̀ mọ́ Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run Bí Pétérù sì ti ń dààmù nínú ara rẹ̀ bí a ìbá ti mọ̀ ìran tí oun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Kọ̀nélíù dé Wọ́n ń bèèrè ilé Símónì, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà Wọn nahùn ń bèèrè bí Símónì tí a ń pè ní Pétérù, wọ̀ níbẹ̀ Bí Pétérù sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ Njẹ́ dìde, sọ̀kalẹ̀ kí ó sì bá wọn lọ, má ṣe kọminú ohunkohun nítorí èmi ni ó rán wọn Nígbà náà ni Pétérù sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ọkùnrin náà tí a rán, ó sì wí pé, Wò ó, èmi ni ẹni tí ẹ̀yin ń wá kín ni ìdí tẹ̀ ti ẹ fi wá Wọ́n sì wí pé, Kọ̀nẹ́líù balógun ọ̀rún, ọkùnrin olóòtọ́, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ní orúkọ́ rere lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn Júù, òun ni a ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ nípasẹ̀ ańgẹ́lì mímọ́, láti ránṣẹ́ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀ àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ Nígbà náà ni ó pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò Níjọ́ kejì, ó sì dìde, ó bá wọn lọ, nínú àwọn arákùnrin ní Jopa sì bá a lọ pẹ̀lú Lọ́jọ́ kejì wọ́n sì wọ Kesaríà, Kọ̀nélíù sì ti ń rétí wọn, ó sì ti pe àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ Ó sì ṣe bí Pétérù ti ń wọlé, Kọ̀nélíù pàdé rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ rẹ̀, ó sì foríbalẹ̀ fún un Ṣùgbọ́n Pétérù gbé e dìde, ó ni, Dìde ènìyàn ni èmi tìkárami pẹ̀lú Bí ó sì ti ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé, ó sì rí àwọn ènìyàn púpọ̀ tí wọ́n péjọ Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ̀yin mọ̀ bí ó ti jẹ́ èèwọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ Júù, láti bá ẹni tí ó jẹ́ ará ilé mìíràn kẹ́gbẹ́, tàbí láti tọ̀ ọ́ wá ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fihàn mi pé, ki èmi má ṣe pé ẹnikẹ́ni ni èèwọ̀ tàbí aláìmọ́ Nítorí náà ni mo sì ṣe wá ní àìjiyàn, bí a ti ránṣẹ́ pè mi ǹjẹ́ mo bèèrè, nítorí kín ní ẹ̀yin ṣe ránṣẹ́ pè mi Kọ̀nẹ́líù sì dáhùn pé, Ní ìjẹrin, mo ń ṣe àdúrà wákàtí kẹ́sàn-án ọjọ́ ni ilé mi títí di idayìí, sì wò ó, ọkùnrin kan aláṣọ, àlà dúró níwájú mi Ó sì wí pé, Kọ̀nélíù, a gbọ́ àdúrà rẹ, ọrẹ-àánú rẹ̀ sì wà ni ìrántí níwájú Ọlọ́run Ǹjẹ́ ránsẹ́ lọ sí Jópà, kí ó sì pe Símónì wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Pétérù ó wọ̀ ní ilé Símónì aláwọ léti òkun nígbà ti ó bá dé, ẹni yóò sọ̀rọ̀ fún ọ Nítorí náà ni mo sì ṣe ránṣẹ́ sì ọ lójúkan náà, ìwọ sì ṣeun tí ó fi wá Gbogbo wa pé níwájú Ọlọ́run nísinsìnyìí, láti gbọ́ ohun gbogbo, ti a pàṣẹ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá Pétérù sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojusajú ènìyàn Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣisẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Isírẹ́lì, nígbà tí a wàásù àlàáfíà nípa Jésù Kírísítì Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Jùdíà, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Gálílì, lẹ́yìn bamitíìsímù ti Jòhánù wàásù rẹ̀ Àní gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run Ẹ̀mi Mímọ́ àti agbára ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí Èṣù sì ń pọ́n lójú nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ Àwa sì ni ẹlẹ́rì gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerúsálémù Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti lọ́wọ́ Ọlọ́run yàn tẹ́lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jindé kúrò nínú òkú Ó sì paṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe Onídàjọ́ ààyè àti òkú Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀ Bí Pétérù sì ti ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́nu, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé gbogbo àwọn ti ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà Ẹnu sì yà àwọn onígbàgbọ́ ti ìkọlà tí wọ́n bá Pétérù wá, nítorí ti a tu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ sórí àwọn aláìkọlà pẹ̀lú Nítorí wọ́n gbọ́, wọ́n ń fọ onírúurú èdè, wọn sì yin Ọlọ́run lógo Nígbà náà ni Pétérù dáhùn wí pé, Ẹnikẹ́ni ha lè ṣòfin omi, kí a má bamítíìsì àwọn wọ̀nyí tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa Ó sì pàsẹ kí a bamitíìsì wọn ni orúkọ Jésù Kírísitì Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró ni ijọ́ mélòókan Pétérù Ṣàlàyé Nípa Àwọn Ìhùwàsí Rẹ̀ Àwọn àpósítélì àti àwọn arákùnrin ti ó wà ni Jùdíà sì gbọ́ pé àwọn aláìkọlà pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Nígbà tí Pétérù sì gòkè wá sí Jerúsálémù, àwọn ti ìkọlá ń bá a wíjọ́ wí pé, Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun Ṣùgbọ́n Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí i là á yé wọn lẹ́sẹẹsẹ, wí pé, Èmi wà ni ìlú Jópà, mo ń gbàdúrà, mo rí ìran kan lójúran Ohun èlò kan sọ̀kalẹ̀ bí ewé tákàdá ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá ó sì wá títí de ọ̀dọ̀ mi Mo tẹjúmọ́ ọn, mo sì fiyèsí i, mo sí rí ẹran ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin, àti ẹranko ìgbẹ́, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run Mo sì gbọ́ ohùn kan ti ó fọ̀ sí mi pé, Dìde, Pétérù máa pa, kí ó sì máa jẹ Ṣùgbọ́n mo dáhùn wí pé, Àgbẹdọ̀, Olúwa! nítorí ohun èèwọ̀ tàbí ohun aláìmọ́ kan kò wọ ẹnu mi rí láí Ṣùgbọ́n ohùn kan dáhùn nígbà ẹ̀ẹ̀kéjì láti ọ̀run wá pé, Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, kí ìwọ má ṣe pè é ní àìmọ́ Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà mẹ́ta a sì tún fa gbogbo rẹ̀ sókè ọ̀run Sì wò ó, lójúkan náà ọkùnrin mẹ́ta dúró níwájú ilé ti a gbé wà, ti a rán láti Kesaríà sí mi Ẹ̀mí sì wí fún mi pé, kí èmi bá wọn lọ, ki èmi má ṣe kọminú ohunkóhun Àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí sì bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà Ó sì sọ fún wa bí òun ti rí ańgẹ́lì kan tí ó dúró ní ilé rẹ̀, tí ó sì wí pé, Ránṣẹ́ lọ sí Jópà, kí ó sì pe Símónì tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Pétérù Ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ fún ọ, nípa èyí tí a ó fi gba ìwọ àti gbogbo ilé rẹ là Bí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sì sọ, Ẹ̀mi Mímọ́ sì bà lé wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ni àtètèkọ́ṣe Nígbà náà ni mo rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí pé, Jòhánù fi omi bamitíìsì nítóòtọ́ ṣùgbọ́n a ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì yín Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run sì ti fi irú ẹ̀bùn kan náà fún wọn bí ó ti fi fún àwa pẹ̀lú nígbà tí a gba Jésù Kírísítì Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí n ó fi rò pé mo le è de Ọlọ́run ní ọ̀nà Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́, wọ́n sì yin Ọlọ́run ógo wí pé, Ǹjẹ́ Ọlọ́run fi ìrònúpíwàdà sí ìyè fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú! Nítorí náà àwọn tí a sì túká kiri ní ti inúnibíni tí ó dìde ní ti Sítéfánù, wọ́n rìn títí de Fonísíà, àti Kípíru, àti Ańtíókù, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnìkan bí kò ṣe fún kìkì àwọn Júù Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Sáípúrọ́sì àti Kírénè nígbà tí wọ́n dé Áńtíókù, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Hélénì pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù Jésù Olúwa Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerúsálémù wọ́n sì rán Bánábà lọ títí dé Áńtíókù Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́ ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa Bánábà sì jáde lọ sí Tásọ́sì láti wá Ṣọ́ọ̀lù, nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Áńtíókù Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọ pọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀ Ní Áńtíókù ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni Kírísítìánì Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn wòlíì sì ti Jerúsálémù sọ̀kalẹ̀ wá sí Áńtíókù Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Ágábù sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Róòmù Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arakùnrin tí ó wà ní Jùdíà Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi i ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù Pétérú Bọ́ Kúrò Ní Ẹ̀wọ̀n Pẹ̀lú Ìyanu Ní àkókò ìgbà náà ni Hérọ́dù ọba sì nawọ́ rẹ̀ mú àwọn kan lójú nínú ìjọ, pẹ̀lú èrò láti pọ́n wọn lójú Ó sì fi idà pa Jákọ́bù arakùnrin Jòhánù Nígbà tí ó sì rí pé èyí ó dùn mọ́ àwọn Júù nińu, ó sì nawọ́ mú Pétérù pẹ̀lú Ó sì jẹ́ ìgbà ọjọ́ àkàrà àìwú Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ Hẹ́rọ́dù ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrekọjá fún ìdájọ́ Nítorí náà wọn fi Pétérù pamọ́ sínú túbú ṣùgbọ́n ìjọ ń fi ìtara gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un Ní òru náà gan-an ti Héródù ìbá sì mú un jáde, Pétérù ń sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀sọ́ sí wà lẹ́nu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà Sì wò ó, ańgẹ́lì Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ́ sì mọ́ nínú túbú ó sì lu Pétérù pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, Dìde kánkán! Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Pétérù Ańgẹ́lì náà sì wí fún un pé, Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ! Pétérù sì ṣe bẹ́ẹ̀ Ó sì wí fún un pé, Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn! Pétérù sì jáde, ó ń tọ ọ lẹ́yìn kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ ańgẹ́lì náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣèbí òun wà lójú ìran Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ ìkínní àti ìkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú Ó sí tikararẹ̀ sí sílẹ̀ fún wọn wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ lójúkan náà ańgẹ́lì náà sì fi í sílẹ̀ lọ Nígbà tí ojú Pétérù sì wálẹ̀, ó ní, Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán ańgẹ́lì rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Héródù àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń rétí! Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Màríà ìyá Johánù, tí àpélè rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ pejọ sí, tí wọn ń gbàdúrà Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Ródà wá láti dáhùn Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Pétérù, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sí sọ pé, Pétérù dúró ní ẹnu-ọ̀nà Wọ́n sì wí fún un pé, Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀! Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́ Wọn sì wí pé, Ańgẹ́lì rẹ̀ ni! Ṣùgbọ́n Pétérù ń kànkùn síbẹ̀, nígbà tí wọn sì ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yá wọ́n Ṣùgbọ́n ó juwọ́ sí wọn pé kí wọn dákẹ́, ó sì ròyìn fún wọn bí Olúwa ti mú òun jáde kúrò nínú túbú Ó sì wí pé Ẹ ro èyí fún Jákọ́bù àti àwọn arákùnrin yòókù! Ó sì jáde, ó lọ sí ibòmíràn Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìrúkèrúdò díẹ̀ kọ́ ni ó wà láàrin àwọn ọmọ-ogun nípa ohun tí ó débá Pétérù Nígbà tí Héródù sì wá a kiri, tí kò sì rí i, ó wádìí àwọn ẹ̀sọ́, ó paṣẹ pé, kí a pa wọ́n Hẹ́rọ́dù sì sọ̀kalẹ̀ láti Jùdíà lọ sí Kesaríà, ó sì wà níbẹ́ fún ìgbà díẹ̀ Héródù sí ń bínú gidigidi sí àwọn ará Tírè àti Sídónì ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀sọ̀kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọn sì ti tu Bílásítù ìwẹ̀fà ọba lójú, wọn ń bẹ̀ẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí pé ìlú ọba náà ni ìlú tiwọn ti ń gba oúnjẹ Ni ọjọ́ àfiyèsí kan, Hẹ́rọ́dù sì wà nínú aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ni orí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ń bá àwọn àjọ ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba Àwọn ènìyàn sì hó wí pé, Ohùn ọlọ́run ni, kì í sì í ṣe ti ènìyàn! Lójúkan náà, nítorí ti Hẹ́rọ́dù kò fi ògo fún Ọlọ́run, ańgẹ́lì Olúwa lù ú, ó sì kú, ìdin sì jẹ ẹ́ Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbilẹ̀, ó sì bí sí i Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù sì padà wá láti Jerúsálémù, nígbà ti wọ́n sì parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, wọn sì mú Jòhánù ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù wá pẹ̀lú wọn A Rán Bánábà Àti Pọ́ọ̀lù Fún Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Áńtíókù Bánábà àti Síméónì tí a ń pè ni Nígérì, àti Lúkíọ́sì ará Kírénè, àti Mánáénì àti Ṣọ́ọ̀lù Bí wọn sì ti ń jọ́sìn fún Olúwa, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ wí pé, Ẹ ya Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù sọ́tọ̀ fún mi fún iṣẹ́ ti mo ti pè wọ́n sí! Nígbà tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, tí wọn sì ti gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti rán àwọn mẹ́jẹ̀èjì lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Séléúkíà láti ibẹ̀ wọ́n sì wọ ọkọ̀-ojú omi lọ sí Sáípúrọ́sì Nígbà ti wọ́n sì wà ni Sálámísì, wọ́n ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní sínágọ́gù àwọn Júù Jòhánù náà sì wà pẹ̀lú wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ fún ìránṣẹ́ wọn Nígbà tí wọ́n sì la gbogbo erékùṣù já dé Páfọ̀, wọ́n rí ọkùnrin kan, oṣó, wòlíì èké, Júù, orúkọ ẹni ti ó ń jẹ́ Baa-Jésù Ó wà lọ́dọ̀ Ségíù Páúlúsì baálẹ̀ ìlú náà, amòye ènìyàn Òun náà ni ó ránṣẹ́ pe Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù, nítorí tí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣùgbọ́n Élímù oṣó takò wọ́n, ó ń fẹ́ pa báalẹ̀ ni ọkàn dà kúrò ni ìgbàgbọ́ Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ti a ń pè ni Pọ́ọ̀lù, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Ẹ́límù, ó sì wí pé, Ìwọ ti ó kún fún àrékérekè gbogbo, àti fún ìwà-ìkà gbogbo, ìwọ ọmọ Èṣù, ìwọ kì yóò ha dẹ́kun láti máa yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po Ǹjẹ́ nísinsin yìí wò ó, ọwọ́ Olúwa ń bẹ lára rẹ̀, ìwọ ó sì fọjú ìwọ kì yóò rí òòrùn ní sáà kan! Lójúkan náà ìkunkùn àti òkùnkùn sí bò ó ó sì ń wá ènìyàn kiri láti fa òun lọ́wọ́ lọ Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Páfòsì wọ́n wá sí Págà ni Pàmífílíà Jòhánù sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerúsálémù Nígbà ti wọ́n sì là Págà kọjá, wọ́n wá sí Pìsìdíà ní Áńtíókù Wọ́n sì wọ inú sínágọ́gù ní ọjọ́ ìsinmi, wọ́n sì jókòó Lẹ́yìn kíka ìwé òfin àti ìwé àwọn wòlíì, àwọn olórí sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé, Ará, bí ẹ̀yin bá ni ọ̀rọ̀ ìyànjú kan fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́! Pọ́ọ̀lù sì dìde dúró, ó sì juwọ́ sí wọn, ó ní, Ẹ̀yin Ísírẹ́lì, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fi etí sílẹ̀ sí mi! Ọlọ́run àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì yìí yan àwọn baba wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà lékè, nígbà tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì, apá gíga ni ó sì fi mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀, ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrú fún ìwà wọn ní ijù, nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kénááni, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní Gbogbo èyí sì sẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àádọ́ta-lé-ní-irínwó ọdún Lẹ̀yìn nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi onídájọ̀ fún wọn, títí ó fi di ìgbà Samueli wòlíì Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì bèèrè ọba Ọlọ́run sì fún wọn ní Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, ọkùnrin kan nínú ẹ̀ya Bẹ́ńjámínì, fún ogójì ọdún Nígbà ti ó sì mú Ṣọ́ọ̀lù kúrò, ó gbé Dáfídì dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, Mo rí Dáfídì ọmọ Jésè ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi Láti inú irú ọmọ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti gbé Jésù Olugbàlà dìde fún Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìlérí Ṣáájú wíwa Jésù ni Jòhánù ti wàásù bamítísímù ìrónúpìwàdà fún gbogbo ènìyàn Isírẹ́lì Bí Jòhánù sì ti ńlá ipa tirẹ̀ já, ó ni, Ta ni ẹ̀yin ṣèbí èmi jẹ́ Èmi kì í ṣe òun Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsí í, ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Ábúráhámù, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí Nítorí àwọn tí ń gbé Jerúsálémù, àti àwọn olórí wọn, nítorí ti wọn kò mọ̀ Jésù, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pílátù láti pá a Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀we nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, Ó sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Gálílì wá sí Jerúsálémù, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsìn yìí fún àwọn ènìyàn Àwa sì mú ìyìn rere wá fún yín pé Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa, Èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jésù dìde Bí a sì ti kọwé rẹ̀ nínú Sáàmù kejì pé  Ìwọ ni Ọmọ mi lónìí ni mo bí ọ Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyí pé  Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dáfídì, tí ó dájú Nítorí ó sì wí nínú Sáàmù mìíràn pẹ̀lú pé  Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́ Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dáfídì ti sin ìran rẹ tan nípa Ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́ Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́ Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jésù yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mósè Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù nítorí èmi ń ṣe iṣẹ́ kan lọ́jọ́ yín, iṣẹ́ tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́ bí ẹnìkan tilẹ̀ ròyìn rẹ̀ fún yín   Bí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì ti ń jáde láti inú sínàgọ́gù, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀ Nígbà tí wọn sì jáde nínú sínágọ́gù, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀le Pọ́ọ̀lù àti Básébà, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ pejọ́ tan lati gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Pọ́ọ̀lù ń sọ Pọ́ọ̀lù àti Básébà sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti paṣẹ̀ fún wa pé  Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà, kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé   Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́ A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbégbé náà Ṣùgbọ́n àwọn Júù rú àwọn obìnrin olùfọkànsìn àti ọlọ́lá sókè àti àwọn àgbà ìlú náà, wọ́n sì gbé inúnibíni dìde sí Pọ́ọ̀lù àti Básébà, wọ́n sì ṣí wọn kúrò ni agbégbé wọn Ṣùgbọ́n wọ́n gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sí wọn, wọn sì wá sí Ikóníónì Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́ Ní Ìkóníónì Ó sí ṣe, ni Ìkóníónì, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà júmọ́ wọ inú sínágọ́gù àwọn Júù lọ, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláìkọlà gbàgbọ́, Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà Nítorí náà Pọ́ọ̀lù àti Bánábà gbé ibẹ̀ pẹ́, wọ́n ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú Olúwa, ẹni tí ó jẹ̀rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ó sì yọ̀ǹda kí iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu máa ti ọwọ́ wọn ṣe Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà pín sí méjì apákan dàpọ̀ mọ́ àwọn Júù, apákan pẹ̀lú àwọn àpósítélì Bí àwọn aláìkọlà, àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn olórí wọn ti fẹ́ kọlù wọ́n láti fi àbùkù kàn wọ́n, àti láti sọ wọ́n ní òkúta, wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sálọ sí Lísírà, àti Dábè, àwọn ìlú Líkáóníà àti sí agbégbé àyíká Níbẹ̀ ni wọ́n sì ń wàásù ìyìn rere Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lísírà, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ń sọ̀rọ̀ ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá Ó wí fún un ní ohùn rara pé, Dìde dúró ṣánsán lórí ẹsẹ̀ rẹ! Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn Nígbà tí àwọn ènìyàn sì rí ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè ni èdè Líkáóníà, wí pé, Àwọn ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wá wá ni àwọ̀ ènìyàn! Wọn sì pe Bánábà ni Ṣeusi àti Pọ́ọ̀lù ni Hamisi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ síṣọ Àlùfáà Júpítérì, ẹni ti ilé òrìsà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn, ó sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu-ibode láti rúbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn àpósítélì wọ̀nyí Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn àpósítélì Bánábà àti Pọ́ọ̀lù gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé Ará, è é ṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìyìn rere fún yín, kí ẹ̀yin baà lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, àti òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà ti wọn Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rúbọ bọ wọ́n Àwọn Júù kan sì ti Áńtíókù àti Ìkóníónì wá, nígbà tí wọ́n yí àwọn ènìyàn lọ́kan padà, wọ́n sì sọ Pọ́ọ̀lù ní òkúta, wọ́n wọ́ ọ kúrò sí ẹ̀yin odi ìlú náà, wọn ṣèbí ó kú Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn dúró ti i yíká, ó dìde ó sì padà wọ inú ìlú náà lọ Ní ọjọ́ kejì ó bá Bánábà lọ sí Dábè Nígbà tí wọ́n sì ti wàásù ìyìn rere fún ìlú náà, tí wọ́n sì ni ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀, wọn padà lọ sí Lísírà, àti Ikóníónì, àti Áńtíókù, wọn sì ń mú àwọn ẹ̀yìn lọ́kàn le, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú láti dúró ní ìgbàgbọ́, àti pé nínú ìpọ̀njú púpọ̀, ni àwa ó fi wọ ìjọba Ọlọ́run Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi à wọ́n lé ẹni gbàgbọ́ Olúwa lọ́wọ́ Nígbà tí wọn sí la Pásídíà já, wọ́n wá sí Páḿfílíà Nígbà tí wọn sì ti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Págà, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ataláyà Àti láti ibẹ̀ lọ wọ́n ṣíkọ̀ lọ sí Ańtíókù ní ibi tí a gbé ti fi wọ́n lé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe parí Nígbà tí wọ́n sì dé, tí wọ́n sì pé ìjọ jọ, wọ́n ròhìn gbogbo ohun tí Ọlọ́run fi wọ́n ṣe, àti bí ó ti ṣí ilẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn aláìkọlà Níbẹ̀ ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni ọjọ́ púpọ̀ Àjọ Ìgbìmọ̀ Ní Jerúsálémù ÀWỌN ọkùnrin kan tí Jùdíà sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì kọ́ àwọn arakùnrin pé, Bí kò ṣe pé a bá kọ yín ni ilà bí ìṣe Mósè, ẹ̀yin kí yóò lè là Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánabà ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú wọn, wọ́n yan Pọ́ọ̀lù àti Bánábà àti àwọn mìíràn nínú àpósítélì kí wọn gòkè lọ sí Jerúsálémù, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Féníkè àti Samaríà kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin Nígbà tí wọn sì dé Jerúsálémù, àti àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn Ṣùgbọ́n àwọn kan ti ẹ̀yà àwọn Farisí tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mósè mọ́ Àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí Nígbà tí iyàn sì di púpọ̀, Pétérù dìde, ó sì wí fún wọn pé, Ará, ẹ̀yin mọ̀ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn nínú yín pé, kí àwọn aláìkọlà lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere láti ẹnu mi, kí wọn sì gbàgbọ́ Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olúmọ-ọkàn, sì jẹ́ wọn lẹ́rìí, ó fún wọn ni Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwa Kò sí fi ìyàtọ̀ sí àárin àwa àti àwọn, ó ń fi ìgbàgbọ́ wẹ̀ wọ́n lọ́kàn mọ́ Ǹjẹ́ nítorí náà è é ṣe tí ẹ̀yin o fi dán Ọlọ́run wò, láti fi àjàgà bọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́rùn, èyí tí àwọn baba wa àti àwa kò lè rù Ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Olúwa Jésù àwa ó là, gẹ́gẹ́ bí àwọn Gbogbo àjọ sí dákẹ́, wọ́n sì fi ẹ̀rí sí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù, tí wọn ń ròyìn iṣẹ́-àṣẹ àti iṣẹ́-àmì tí Ọlọ́run tí ti ọwọ́ wọn ṣe láàrin àwọn aláìkọlà Lẹ̀yìn tí wọn sì dákẹ́, Jákọ́bù dáhùn, wí pé, Ará, ẹ gbọ́ tèmi Símóòní ti róyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojúwo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀ Báyìí ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì bá ṣe dédé bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni èmi ó padà, èmi ó sì tún àgọ́ Dáfídì pa tí ó ti wó lulẹ̀ èmi ó sì tún ahoro rẹ̀ kọ́, èmi ó sì gbé e ró kí àwọn ènìyàn ìyókù lè máa wá Olúwa, àti gbogbo àwọn aláìkọlà tí a ń fi orúkọ mi pè ni Olúwa wí, ta ni ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí Ní Olúwa wí, ẹni tí ó sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí di mímọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ wá, Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fà sẹ̀hín kúrò nínú èérí òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀ Mósè nígbà àtijọ́, sá ní àwọn ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú sínágọ́gù ni ọjọ́jọ́ ìsinmi Nígbà nàá ni ó tọ́ lójú àwọn àpósítélì, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Áńtíókù pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù àti Bánábà Júdà ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Básábà, àti Sílà, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin Wọn sì kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́ báyìí pé Àwọn àpósítélì, àti àwọn alàgbà, Tí ó jẹ̀ ti aláìkọlà tí ó wà ní Áńtíókù, àti ní Síríà àti ní Kílíkíà Níwọ̀n bí àwa ti gbọ́ pé, àwọn kan ti ó ti ọ̀dọ̀ wa jáde wá ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n ń yí yín lọ́kàn po, ẹni tí àwa kò fún ní àṣẹ Ó yẹ lójú àwa, bí àwa ti fi ìmọ̀ sọ̀kan láti yan ènìyàn láti rán wọn sí yín, pẹ̀lú Bánábà àti Pọ́ọ̀lù àwọn olùfẹ́ wa Àwọn ọkùnrin ti ó fi ọkàn wọn wéwu nítorí orúkọ Olúwa wa Jésù Kírísítì Nítorí náà àwa rán Júdà àti Sílà àwọn tí yóò sì fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ ohun kan náà fún yín Nítorí ó dára lójú Ẹ̀mí Mímọ́, àti lójú wa, kí a má ṣe di ẹrù kà yín, bí kò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣe pàtàkì Kí ẹ̀yin fà sẹ̀yìn kúrò nínú ẹran àpabọ òrìṣà, àti nínú ẹ̀jẹ̀ àti nínú ohun ìlọ́lọ́rùn-pa, àti nínú àgbérè nínú ohun tí, bí ẹ̀yin bá pa ara yín mọ́ kúrò, ẹ̀yin ó ṣe rere Àlàáfíà Ǹjẹ́ nígbà tí wọ́n sì fi wọ́n sílẹ̀ láti lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá si Áńtíókù nígbà tí wọn sì pé àwọn ìjọ pọ̀, wọn fi ìwé náà fún wọn Nígbà tí wọn sì kà á, wọ́n yọ̀ fún ìtùnú náà Bí Júdà àti Sílà tìkara wọn ti jẹ́ wòlíì pẹ̀lú, wọ́n fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gba àwọn arákùnrin níyànjú, wọ́n sì mú wọn lọ́kàn le Nígbà tí wọn sì pẹ́, díẹ̀, àwọn arákùnrin rán wọn padà lọ ni àlàáfíà sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì dúró díẹ̀ ni Ańtíókù, wọ́n ń kọ́ní, wọ́n sì ń wàásù ọ̀rọ̀, Olúwa, àti àwọn púpọ̀ mìíràn pẹ̀lú wọn Lẹ́yìn ọjọ́ mélóòkán Pọ́ọ̀lù sì sọ fún Bánábà pé, Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa Bánábà sì pinnu rẹ̀ láti mú Jòhánù lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni Páḿfílíà, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì Bánábà sì mu Máàkù ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Sáípúrọ́sì Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù yan Sílà, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin Ó sì la Síríà àti Kílíkíà lọ, ó ń mú ìjọ ní ọkàn le Tìmótíù Darapọ̀ Mọ́ Pọ́ọ̀lù Àti Sílà Ó sì wá sí Dábè àti Lísírà sí kíyèṣi i, ọmọ-ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀, tí a ń pè ní Tìmótíù, ọmọ obìnrin kan tí í ṣe Júù, tí ó gbàgbọ́ ṣùgbọ́n Gíríkì ní baba rẹ̀ Ẹni tí a ròhìn rẹ̀ ní rere lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí ó wà ní Lísírà àti Ìkóníónì Òun ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí ó bá òun lọ ó sì mú un, ó sì kọ ọ́ ní ilà, nítorí àwọn Júù tí ó wà ní agbégbé wọ̀nyí nítorí gbogbo wọn mọ̀ pé, Gíríkì ni baba rẹ̀ Bí wọn sì ti ń la àwọn Ìlú lọ, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ, tí a tí pinnu láti ọ̀dọ̀ àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà tí ó wà ní Jerúsálémù, lé wọn lọ́wọ́ láti máa pa wọ́n mọ́ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ sì fẹsẹmúlẹ̀ ní ìgbágbọ́, wọn ṣí ń pọ̀ sí i ní iye lójoojumọ́ Wọ́n sì la agbégbé Fírígíà já, àti Gálátíà, nítorí tí Ẹ̀mí Mímọ́ kọ̀ fún wọn láti ṣọ ọ̀rọ̀ náà ni Éṣíà Nígbà tí wọ́n dé ọ̀kánkán Mísíà, wọ́n gbìyànjú láti lọ ṣí Bítíníà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Jéṣù kò gbà fún wọn Nígbà tí wọ́n sì kọjà lẹ́bá Mísíà, wọ́n ṣọ̀kalẹ̀ lọ ṣi Tíróásì Ìran kan si hàn sì Pọ́ọ̀lù ni òru Ọkùnrin kan ará Makedóníà dúró, ó sì ńbẹ̀ ẹ̀, wí pé, Rékọjá wá ṣí Makedóníà, kí o sí ràn wá lọ́wọ́! Nígbà tí ó sì tí rí ìran náà, lọ́gán ó múra láti lọ sí Makedóníà, a gbà á sí pé, Olúwa tí pè wá láti wàásù ìyìn rere fún wọn Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Tíróáṣì a ba ọ̀nà tàrà lọ ṣí Sámótírakíà, ni ijọ́ kéjì a sì dé Níápólì Láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Fílípì, Ìlú kan tí tẹ̀dó tí í ṣe olú ìlú yìí fún ọjọ́ mélòókán Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà àwa sí jókóò, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ ṣọ̀rọ̀ Àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Lìdíà, tí ó ń ta àwọn aró ẹlẹ́ṣè àlùkò, gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ọkàn ẹni tí Olúwa ṣí láti fetísì ohun tí a tí ẹnu Pọ́ọ̀lù sọ Nígbà tí a sí bamitíìsì rẹ̀, àti àwọn ara ilé rẹ̀, ó bẹ̀ wá, wí pé, Bí ẹ̀yin bá kà mí ni olóòtọ́ sí Olúwa, ẹ wá si ilé mi, kí ẹ sí wọ̀ níbẹ̀! O sí rọ̀ wá Bí àwa tí nlọ ṣí ibi àdúrà náà, ọmọbìnrin kan tí o ní ẹ̀mí ìwosẹ́, pàdé wa, ẹni tí ó fi àfọ̀ṣẹ mú èrè púpọ̀ wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀ Òun náà ni ó ń tọ Pọ́ọ̀lù àti àwa lẹ́hìn, ó sì ń kígbe, pé, Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni ìránṣẹ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ń kéde ọ̀nà ìgbàlà fún yin! Ó sì ń ṣe èyí lọ́jọ́ púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí inú Pọ́ọ̀lù bàjẹ́, tí ó sì yípadà, ó wí fún ẹ̀mí náà pé, Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jéṣù Kíríṣítì kí o jáde kúrò lára rẹ̀! Ó sí jáde ni wákàtí kan náà Nígbà tí àwọn ọ̀gá rẹ̀ sì ríì pé, ìgbẹ́kẹ̀lé èrè wọn pin, wọ́n mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà, wọn sì wọ́ wọn lọ sí ọjà tọ àwọn aláṣẹ lọ Nígbà tí wọ́n sì mú wọn tọ àwọn onídájọ́ lọ, wọ́n wí pé, Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí í ṣe Júù, wọ́n ń yọ ìlú wa lẹ́nu jọjọ Wọ́n sí n kọ́ni ní àṣà tí kò yẹ fún wa, àwa ẹni tí í ṣe ara Romu, láti gbà àti láti tẹ̀lé Ọ̀pọ̀ ènìyàn sí jùmọ̀ dìde sì wọn àwọn olórí sí fà wọ́n láṣọ ya, wọ́n sí pàṣẹ pé, ki a fí ọ̀gọ̀ lù wọ́n Nígbà tí wọ́n sì lù wọ́n púpọ̀, wọ́n sọ wọ́n sínú túbú, wọ́n kìlọ̀ fún onítúbú kí ó pa wọ́n mọ́ dáradára Nígbà tí ó gbọ́ irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ̀ wọ́n ṣínú túbú tí inú lọ́hùn, ó sí kan àbà mọ wọ́n lẹ́ṣẹ̀ Ṣùgbọ̀n láàrin ọ̀gànjọ́ Pọ́ọ̀lù àti Ṣílà ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpilẹ̀ ile túbú mì tìtì lọ́gán, gbogbo ilẹ̀kùn sì sí, ìde gbogbo wọn sì tú ṣílẹ̀ Nígbà tí onítúbú si tají, tí o sì ri pé, àwọn ìlẹ̀kùn túbú tí sí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣebí àwọn ara túbú ti sá lọ Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù gbé ohun rẹ̀ sókè, wí pé, Má se pa ara rẹ lára nítorí gbogbo wa ń bẹ níhìn yìí! Nígbà tí ó sì beere iná, ó bẹ́ wọ inú ilé, ó ń wárìrì, ó wólẹ̀ níwájú Pọ́ọ̀lù àti Sílà Ó sì mú wọn jáde, ó ní, Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là Wọ́n sì wí fún un pé, Gbá Jéṣù Kírísítì Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là, ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ pẹ̀lú Wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un, àti fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ Ó sì mú wọn ní wákàtí náà lóru, ó wẹ ọgbẹ́ wọn a ṣi bamitíìsì rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójúkan náà Ó sì mú wọn wá ṣí ilé rẹ̀, ó sì gbé ounjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́ Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn onídájọ́ rán àwọn ọlọ́pàá pé, Tú àwọn ènìyàn náà ṣílẹ̀ Onítúbú sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Pọ́ọ̀lù, wí pé, Àwọn onídájọ́ ránṣẹ́ pé kí á da yín ṣílẹ̀ ǹjẹ́ nisinsìnyìí ẹ jáde kí ẹ sì máa lọ ní àlàáfíà Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù wí fún wọn pé, Wọ́n lù wá ni gbangba, wọ́n sì sọ wá sínú túbú ni àìjẹ̀bí, àwa ẹni tí ì ṣe ara Róòmù ṣe nísinsìnyìí wọ́n fẹ́ tì wá jáde nikọ̀kọ̀ Àgbẹdọ̀! Ṣùgbọ́n kí àwọn tìkara wọn wá mú wa jáde! Àwọn ọlọ́pàá sì sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn onídàjọ́ ẹ̀rù sì bà wọ́n, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ará Róòmù ni wọ́n Wọ́n sì wá, wọ́n sìpẹ̀ fún wọ́n, wọn sì mú wọn jáde, wọ́n sì bẹ̀ wọ́n pé, ki wọn jáde kúrò ni ìlú náà Wọ́n sì jáde nínú túbú, wọ́n sì wọ ilé Lídíà lọ nígbà tí wọn sì tí rí àwọn arákùnrin, wọ́n tù wọ́n nínú, wọn sì jáde kúrò Ní Tẹsalóníkà Nígbà tí wọn sì ti kọjá Áḿfípólì àti Apolóníà, wọ́n wá sí Tẹsalóníkà, níbi tí sínágọ́gù àwọn Júù wà Àti Pọ́ọ̀lù, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé-mímọ́ Ó ń túmọ̀, ó sí n fihàn pé, Kíríṣítì kò lè sàìmá jìyà, kí o sì jínde kúrò nínú òkú àti pé, Jéṣu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kírísítì náà A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í se díẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn si fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ìta ènìyàn mọ́ra, wọ́n gbá ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú wọ́n sì kọlu ilé Jásónì, wọ́n ń fẹ́ láti mú wọn jáde tọ àwọn ènìyàn lọ Nìgbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jásónì, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò wá sí ìhínyìí pẹ̀lú Àwọn ẹni tí Jásónì gbà sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kéṣárì, wí pé, ọba mìíràn kan wà, Jéṣù Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ni ìbàlẹ̀ àyà nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí Nígbà tí wọ́n sì gbà ògo lọ́wọ́ Jásónì àti àwọn ìyókù, wọ́n fi wọ́n ṣílẹ̀ lọ Lọ́gán àwọn arákùnrin sì rán Pọ́ọ̀lù àti Ṣílà lọ ṣí Béróéá lóru nígbà tí wọ́n sí dé ibẹ̀, wọ́n wọ inú ṣínágógù àwọn Júù lọ Àwọn wọ̀nyí sì ní ìyìn ju àwọn tí Tẹsalóníkà lọ, ní tí pé wọn fi tọkàntọkàn gbà ọ̀rọ̀ náà Wọ́n sì ń wá inú ìwé-mímọ̀ lójoojúmọ́ bí ǹkan wọ̀nyí bá rí bẹ́ẹ̀ Nítorí náà púpọ̀ nínú wọn gbàgbọ́ àti nínú àwọn obìnrin Gíríkì ọlọ́lá, àti nínú àwọn ọkùnrin, kì í ṣe díẹ̀ Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù tí Tẹsalóníkà mọ̀ pé, Pọ́ọ̀lù ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Béreóà, wọ́n wá síbẹ̀ pẹ̀lú, wọ́n rú àwọn ènìyàn sókè Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rán Pọ́ọ̀lù jáde lọ́gán láti lọ títí de òkun ṣùgbọ́n Sílà àti Tímótíù dúró ṣíbẹ̀ Àwọn tí ó sin Pọ́ọ̀lù wá sì mú un lọ títí dé Átẹ́nì nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sílà àti Tímótíù pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dúró dè wọ́n ni Aténì, ẹ̀mí rẹ̀ ru nínú rẹ̀, nígbà tí ó rí pé ìlú náà kún fún òrìṣà Nítorí náà ó ń bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú Sínágógù, àti àwọn olùfọkànsìn, àti àwọn tí ó ń bá pàdé lọ́jà lójoojúmọ́ Nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Épíkúrè àti tí àwọn Sítííkì pàdé rẹ̀ Àwọn kan si ń wí pé, Kín ni aláhesọ yìí yóò rí wí Àwọn mìíràn sì wí pé, Ó dàbí ń wàásù Jésù, àti àjíǹde fún wọn Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fà á lọ ṣí Áréópágù, wọ́n wí pé, A ha lè mọ̀ kín ni ẹ̀kọ́ titun tí ìwọ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́ Nítorí tí ìwọ mú ohun àjèjì wá si etí wa àwa sì ń fẹ́ mọ̀ kín ni ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí Nítorí gbogbo àwọn ará Áténì, àti àwọn àlejò tí ń ṣe àtìpó níbẹ̀ kì í ṣe ohun mìíràn jù kí a máa sọ tàbí ki a máa gbọ́ ohun titun lọ Pọ́ọ̀lù si dìde dúró láàrin Áréópágù, ó ní, Ẹ̀yin ará Áténì, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún onírúurú ìsìn jù Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí ṣí, FÚN ỌLỌ́RUN ÀÌMỌ̀ Ǹjẹ́ ẹni tí ẹyin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń ṣọ fún yin Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́ Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn Ó sì tí tipàṣẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn kí wọ́n baà lè maa wá Olúwa, bóyá wọn yóò lè sàfẹrí rẹ̀, ki wọn sì rí í Bí ó tílẹ̀ jẹ pé kò jìnnà sí olúkúlùkù wa Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láàyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkarayín tí wí pé, Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀ Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, Ẹni-Ijọ́sìn-sí wa dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya èré àwòrán rẹ̀ Pẹ̀lúpẹ̀lù ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí gbójú fò dá ṣùgbọ́n nísìnyìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà Níwọ̀n bí ó ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé lódodo nípaṣẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn, nígbà tí ó ti fi ohun ìdánilójú fún gbogbo ènìyàn, níti pé ó jí dìde kúrò nínú òkú Nígbà tí wọ́n ti gbọ́ ti àjíǹde òkú, àwọn mìíràn ń ṣẹ̀fẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn mìíràn wí pé, Àwa o tún nǹkan yìí gbọ́ lẹ́nu rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù sì jáde kúrò láàrin wọn Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin kan fi ara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́ nínú àwọn ẹni tí Díónísíù ara Aréópágù wà, àti obìnrin kan tí a ń pè ni Dámárì, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn Ní Kóríntì Lẹ́yin nǹkan wọ̀nyí, Pọ́ọ̀lù jáde kúrò ni Aténì, lọ sí Kọ́ríńtì Ó sì rí Júù kan tí a ń pè ní Àkúílà, tí a bí ni Pọ́ńtù, tí ó ti Ìtalì dé ní lọ́ọ́lọ́ọ́, pẹ̀lú Pírísíkílà aya rẹ̀ nítorí tí Kíláúdíù pàsẹ pé, kí gbogbo àwọn Júù jáde kúrò ní Róòmù Ó sì tọ̀ wọ́n lọ láti rí wọn Nítorí tí òun náà jẹ́ onísẹ̀-ọwọ́ kan náà, ó bá wọn jókòó, ó sì nṣíṣẹ́ nítorí àgọ́ pípa ni iṣẹ́-ọwọ́ wọn Ó sì ń fọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ fún wọn nínú ṣínágógù lọ́jọjọ́ ìsinmi, ó sì ń yí àwọn Júù àti àwọn Gíríkì lọ́kàn padà Nígbà tí Sílà àti Tímótíù sì tí Makedóníà wá, ọ̀rọ̀ náà ká Pọ́ọ̀lù lára, ó ń fi hàn fún àwọn Júù pé, Jésù ni Kírísítì náà Nígbà tí wọ́n sì sàtakò rẹ̀, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì, ó gbọ́n aṣọ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ̀jẹ̀ yin ń bẹ lórí ara yin ọrùn èmi mọ́ láti ìsinsìnyìí lọ, èmi yóò tọ àwọn aláìkọlà lọ Ó sì lọ kúrò níbẹ, ó wọ ile ọkùnrin kan tí a ń pé ní Títù Júsù, ẹni tí o ń sin Ọlọ́run ilé rẹ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ Sínágógù tímọ́tímọ́ Kírísípù, olórí ṣínágọ́gù, sì gba Olúwa gbọ́ pẹ̀lú gbogbo ilé rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ nínú àwọn ara Kọ́ríńtì, nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbàgbọ́, a sì bamitíìsì wọn Olúwa sì sọ fún Pọ́ọ̀lù lóru ni ojúran pé, Má bẹ̀rù, sá máa sọ, má sì se pá ẹnu rẹ̀ mọ́ Nítorí tí èmí wà pẹ̀lú rẹ, kò sì sí ẹni tí yóò dìde sí ọ láti pa ọ lára nítorí mo ní ènìyàn púpọ̀ ni ìlú yìí Ó sì jókòó níbẹ̀ ní ọdun kan àti oṣù mẹ́fà, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàrin wọn Nígbà tí Gálíónì sì jẹ báalẹ̀ Ákáyà, àwọn Júù fi ìfìmọ̀ṣọ̀kan dide sí Pọ́ọ̀lù wọn sì mú un wá síwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Wọ́n wí pé, Ọkùnrin yìí ń yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, láti máa sin Ọlọ́run lòdì sí òfin Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fẹ́ dáhùn, Gálíónì wí fún àwọn Júù pé, Ìbá ṣe pé ọ̀ràn búburú tàbí tí jàgídíjàgan kan ni, èmi ìbá gbè yín, ẹyin Júù Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀ràn nipa ọ̀rọ̀ àti orúkọ, àti ti òfin yín ni, ki ẹ̀yin bojútó o fúnrará yín nítorí tí èmi kò fẹ ṣe onídàjọ́ nǹkan báwọ̀nyí Ó sì lé wọn kúrò ní ibi ìtẹ́ ìdájọ́ Gbogbo àwọn Gíríkì sì mú Sósìténì, olórí ṣínágógù, wọ́n sì lù ú níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Gálíónì kò sì bìkítà fún nǹkan wọ̀nyí Pọ́ọ̀lù sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀-ojúomi lọ si Síríà, àti Pìrìsílà àti Àkúílà pẹ̀lú rẹ̀ ó tí fá orí rẹ̀ ni Kéníkíríà nítorí tí o tí jẹ́jẹ̀ẹ́ Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Éféṣù, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀ ṣùgbọ́n òun tìkararẹ̀ wọ inú Sínágọ́gù lọ, ó sì bá àwọn Júù fí ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ Nígbà tí wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó bá àwọn jókòó díẹ̀ sí i, ó kọ̀ Ṣùgbọ́n ó dágbére fún wọn, ó sì wí pé, Èmi ó tún padà tọ̀ yín wá, bí Ọlọ́run bá fẹ́ Ó sì ṣíkọ̀ láti Éfésù Nígbà tí ó sì tí gúnlẹ̀ ni Keṣaríà tí ó gòkè, tí ó sì kí ijọ, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sì Áńtíókù Nígbà tí ó sì gbé ọjọ́ díẹ̀ níbẹ, ó lọ, ó sì kọjá lọ láti Gálátíà àti Fírígíà, ó mú gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le Júù kan sì wà tí a ń pè ni Àpólò, tí a bí ni Alekisáńdíríà, ó wá sí Éféṣù Ó nì ẹ̀bùn ọ̀rọ̀-sísọ, ó sì mọ ìwé mímọ́ púpọ̀ Ọkùnrin yìí ni a tí kọ́ ní ọ̀nà tí Olúwa ó sì ṣe ẹni tí ó ní ìtara tí ẹ̀mí, ó ń sọ̀rọ̀ ó sì ń kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Olúwa dáradára kìkì bamitíìsímù tí Jòhánù ní ó mọ̀ Ó sì bẹ̀rẹ̀ ṣí fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni Sínágọ́gù nígbà tí Àkúílà àti Pìrìskílà gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un sọ́dọ̀ wọ́n sì túbọ̀ sọ ọ̀nà Ọlọ́run fún un dájúdájú Nígbà tí ó sì ń fẹ́ kọjá lọ sì Ákáyà, àwọn arakùnrin gbà á ní ìyànjú, wọ́n sì kọ̀wé sí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn kí wọ́n gbà á nígbà tí ó sì dé, ó ràn àwọn tí ó gbàgbọ́ nípasẹ̀ oore-ọfẹ lọ́wọ́ púpọ̀, Nítorí tí o sọ àsọyé fún àwọn Júù ní gbangba, ó ń fi í hàn nínú ìwé-mímọ́ pé, Jésù ni Kíríṣítí Pọ́ọ̀lù Ní Éfésù Nígbà ti Àpólò wà ni Kọ́ríńtì, ti Pọ́ọ̀lù kọjá lọ sí apá òkè-ìlú, ó sì wá ṣí Éfésù o sì rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kan Ó wí fún wọn pé, Ẹ̀yin ha gba Ẹ̀mi Mímọ́ náà nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́ Wọ́n sì wí fún un pé, Àwa kò gbọ́ rárá pé Ẹ̀mí Mímọ́ kan wà Ó sì wí pé, Ǹjẹ́ irú bamítíìsímù wo ni a bamitíìsímù yín sí Wọ́n sì wí pé, Sí bamitíìsímù tí Jòhánù Pọ́ọ̀lù sí wí pé, Nítọ̀ọ́tọ́, ní Jòhánù fi bamitíìsímù tí ìrònúpìwàdà bamitíìsímù, ó ń wí fún àwọn ènìyàn pé, kí wọ́n gba ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́, èyí sì ni Kírísítì Jésù Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, a bamitíìsímù wọn lórúkọ Jéṣù Olúwa Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn wọ́n sì ń fọ́ èdè mìíràn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ Iye àwọn ọkùnrin náà gbogbo tó méjìlá Nígbà tí ó sì wọ inú Sínágọ́gù lọ ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni oṣù mẹ́ta, ó ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó sì ń yí wọn lọ́kàn padà sí nǹkan tí i ṣe tí ìjọba Ọlọ́run Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoójúmọ́ ni ilé-ìwé Tíráńnù Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Éṣíà gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Gíríkì Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Pọ́ọ̀lù ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyànu, Tóbẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti ìbàǹtẹ́ ara rẹ̀ tọ àwọn ọlọ́kùnrùn lọ, àrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan alárìnkiri, alẹ́mìí-èṣù jáde, bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ni àdábọwọ́ ara wọn, láti pé orúkọ Jésù Olúwa sí àwọn tí ó ni ẹ̀mí búburú, wí pé, Àwa fi orúkọ Jésù tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù fi yín bú Àwọn méje kan sì wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹnìkan tí a ń pè ni Síkẹ́fà, Júù, tí í ṣe olórí àlùfáà gíga Ẹmí búburú náà sì dáhùn, ó ní Jéù èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin Nígbà tí ọkùnrin tí ẹ̀mí búburú náà wà lára rẹ̀ sì fò mọ́ wọn, ó pá kúúrù mọ́ wọn, ó sì borí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sá jáde kúrò ní ilé náà ní ìhòòhò pẹ̀lú ni ìfarapa Ìròyìn yìí sì di mímọ̀ fún gbogbo àwọn Júù àti àwọn ará Gíríkì pẹ̀lú tí ó ṣe àtìpó ní Éfésù ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn, a sì gbé orúkọ Jésù Olúwa ga Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ sì wá, wọ́n jẹ́wọ́, wọ́n sì fi iṣẹ́ wọn hàn Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí ń se alálùpàyídà ni ó kó ìwé wọn jọ, wọ́n dáná sun wọ́n lójú gbogbo ènìyàn wọ́n sì sirò iye wọn, wọ́n sì rí i, ó jẹ́ ẹgbàámẹ́ẹ̀dọ́gbọ́n ìwọ̀n fàdákà Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa gbérú tí o sí gbilẹ̀ si í gidigidi Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Pọ́ọ̀lù pínnu nínú ẹ̀mí rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedóníà àti Ákáyà, òun ó lọ sí Jerúsálémù, ó wí pé, Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàì má dé Róòmù pẹ̀lú Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ ṣí Makedóníà, Tímótíù àti Érásítù, òun tìkararẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Éṣíà Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Démétíríù, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé-òrìṣà fún Dáyánà, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọ̀nà bẹ́ẹ̀, ó ní, Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nipa iṣẹ́-ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Éfésù nìkanṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹrẹ jẹ́ gbogbo Éṣíà, ni Pọ́ọ̀lù yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run Kì í sì ṣe pé kìkí iṣẹ́-ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí aṣán ṣùgbọ́n ilé Dáyánà òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọlá-ńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Éṣíà àti gbogbo ayé ń bọ Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, Òrìṣà ńlá ni Dáyánà ti ará Éfésù! Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò wọ́n sì fi ipa fa Gáíù àti Árísítaríkù ara Makedóníà lọ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù nínú ìrìn-àjò Nígbà ti Pọ́ọ̀lù sì ń fẹ́ wọ àárin àwọn ènìyàn lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀ fún un Àwọn olórí kan ara Éṣíà, tí i ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ránṣẹ́ sí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe fi ara rẹ̀ wéwu nínú ilé ibi-ìṣeré náà Ǹjẹ́ àwọn kan ń wí ohun kan, àwọn mìíràn ń wí òmíran nítorí àjọ di rúdurùdu ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò sì mọ̀ ìdí ohun tí wọ́n tilẹ̀ fi péjọ pọ̀ Àwọn kan nínú àwujọ ń gún Alekisáńdérù, tí àwọn Júù tì síwájú, ní kẹ́ṣẹ́ láti ṣọ̀rọ̀ Alekisáńdérù sì juwọ́ sì wọn, òun ìbá sì wí ti ẹnu rẹ̀ fún àwọn ènìyàn Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Júù ni, gbogbo wọn, ni ohùn kan, bẹ̀rẹ̀ ṣí kígbe fún bi wákàtí méjì pé, Òrìṣà ńlá ni Dáyánà tí ará Éfésù! Nígbà tí akọ̀wé ìlú sì mú kí ìjọ ènìyàn dákẹ́, ó ní, Ẹ̀yin ará Éfésù, ta ni ẹni tí ó wà tí kò mọ̀ pé, ìlú ará Éfésù ní í ṣe olùsìn Dáyánà òrìṣà ńlá, àti tí ère tí ó ti ọ̀dọ̀ Júpítérì bọ́ sílẹ̀ Ǹjẹ́ bi a kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí nǹkan wọ̀nyí, ó yẹ kí ẹ dákẹ́, kí ẹ̀yin má ṣe fi ìwara ṣe ohunkohun Nítorí ti ẹ̀yin mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wá, wọn kò ja ilé òrìṣà lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ṣọ̀rọ̀-òdì ṣí òrìṣà wa Ǹjẹ́ nítorí náà tí Démétíríù, àti àwọn oníṣẹ́-ọnà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní gbólóhùn-asọ̀ kan sí ẹnìkẹ́ni, ilé-ẹjọ́ ṣí sílẹ̀, àwọn onídájọ́ sì ń bẹ jẹ́ kí wọn lọ fi ara wọn sùn Ṣùgbọ́n bí ẹ ba ń wádìí ohun kan nípa ọ̀ràn mìíràn, a ó parí rẹ̀ ni àjọ tí ó tọ́ Nítorí àwa ṣa wà nínú èwu, nítórí rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ lóní yìí kò sáá ní ìdí kan tí ìwọ́jọ yìí fi bẹ́ sílẹ̀ Nígbà tí ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tan, ó tú ìjọ náà ká Ẹ̀mí-Mímọ́ Wá Ní Pẹńtíkọ́sítì Nígbà tí ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sítì sì dé, gbogbo wọn fi ọkàn kan wà ní ibìkan Lójijì ìró sì ti ọ̀run wá, gẹ́gẹ́ bí ìró ẹ̀fúùfù líle, ó sì kún gbogbo ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó Ẹ̀là ahọ́n bí i iná sì yọ sí wọn, ó pín, ó sì bà lé olúkúlùkù wọn Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn ni ohùn Àwọn Júù olùfọkànsìn láti orílẹ̀-èdè gbogbo lábẹ́ ọ̀run sì ń gbé Jerúsálémù Nígbà tí wọn sì gbọ́ ìró yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ nínú ìdàmú, nítorí tí olúkúlùkù gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè rẹ̀ Ẹnu sì yà wọ́n, wọn ń wí fún ara wọn pé, Ǹjẹ́ ara Gálílì kọ́ ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́ Èé ha sì tí ṣe ti olúkúlùkù wa fi ń gbọ́ bí wọ́n tí ń fi èdè sọ̀rọ̀ Àwọn ará Pátíríà, àti Médísì, àti Élámù àti àwọn tí ń gbé Mesopotamíà, Júdíà, àti Kapadókíà, Pọ́ńtù, àti Ásíà Fírígíà, àti Pàḿfílíà, Íjíbítì, àti agbégbé Líbíà níhà Kírénè àti àwọn àtìpó Róòmù, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù Àwọn ara Kírétè àti Árábíà àwa gbọ́ tí wọ́n sọ́rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n aì wá rìrì Wọn wí fún ara wọn pé, Kí ni èyí túmọ̀ sí Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmìíràn ń sẹ̀fẹ̀, wọn sí wí pé, Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì titun Nígbà náà ni Pétérù díde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá yòókù, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ̀yin Júù ènìyàn mi àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé Jerúsálémù, ẹ jẹ́ kí èyí kí ó yé yin kí ẹ sì fétísí ọ̀rọ̀ mi Àwọn wọ̀nyí kò mutí yó, bí ẹ̀yin tí ròó wákàtí kẹ́ta ọjọ́ sáà ni èyí Bẹ́ẹ̀ kọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ ti a ti sọ láti ẹnu wòlíì Joeli  Ní ìkẹyìn ọjọ́, Ọlọ́run wí pé, Èmi yóò tú Ẹ̀mí mí jáde sára ènìyàn gbogbo, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò sì máa ríran, àwọn arúgbó yín yóò sì máa lá àlá Àti sára àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mi ọkùnrin àti sára àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mi obìnrin, ni Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi jáde ni àwọn ọjọ́ náà wọn yóò sì máa sọtẹ́lẹ̀ Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn lójú ọ̀run, àti àwọn àmì nísàlẹ̀ ilẹ̀ ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín A yóò sọ òòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé Yóò sì ṣe pé ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí Jésù tí Násárẹ́tì, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti àmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín, bí ẹ̀yin tíkárayín ti mọ̀ pẹ̀lú Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀yin pẹ̀lú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú kàn mọ́ àgbélébùú, tí a sì pa á Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí díde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dì í mú Dáfídì tí wí nípa tirẹ̀ pé  Mo rí Olúwa nígbà gbogbo niwájú mí, nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi, A kì ó ṣí mi ní ipò Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀ pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà-òkú, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni-Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́ Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè, ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ Ará, èmí lè sọ fún yin pẹ́lú ìgboyà pé ní ti Dáfídì baba ńlá kú, a sì sin ín, ibojì rẹ̀ sì ń bẹ lọ́dọ̀ wa títí di òní yìí Ṣùgbọ́n ó jẹ́ wòlíì, àti bí ó mọ́ pé, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún òun nínú ìbúra pé nínú irú-ọmọ inú rẹ̀, òun yóò mú ọ̀kan jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ Ní rírí èyí tẹ́lẹ̀, ó sọ ti àjíǹde Kírísítì, pé a kò fi ọkan rẹ̀ sílẹ̀ ni isà-òkú, bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́ Jésù náà yìí ni Ọlọ́run ti jí díde sí ìyè, àwa pẹ̀lú sì jẹ́rìí sí èyí A ti gbé ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó tu èyí tí ẹ̀yin rí àti gbọ́ nísinsìyìí sítá Nítorí Dáfídì kò gókè lọ sí ọ̀run ṣùgbọ́n òun tìkárarẹ̀ wí pé,  Olúwa wí fún Olúwa mi pé Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀ta rẹ dí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ   Ǹjẹ́ kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run ti fi Jésù náà, ti ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, se Olúwa àti Kírísítì Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ́, wọn sì wí fún Pétérù àti àwọn àpósítélì yòókù pé, Ará, kín ni àwa yóò ṣe Pétérù sì wí fún wọn pé, Ẹ ronúpìwàdà, kí a sì bamitíìsì olúkúkùkù yín ní orúkọ Jésù Kírísítì fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín Ẹ̀yin yóò sì gba ẹbun Ẹ̀mí Mímọ́ Nítorí fún yín ni ìlérí náà, àti fún àwọn ọmọ yín, àti fún gbogbo àwọn tí ó jìnnà réré, àní gbogbo àwọn tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò pè Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀ mìíràn ni ó fi ń kìlọ̀ tí ó sì ń fi ń rọ̀ wọ́n wí pé, Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí Nítorí náà àwọn tí ó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a bamítíìsì wọn, lọ́jọ́ náà a sì kà ìwọn ẹgbẹ̀rùn mẹ́ta ọkàn kún wọn Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn àpósítélì, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà Ẹ̀rù sí ba gbogbo ọkàn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì púpọ̀ ni a ti ọwọ́ àwọn àpósítélì ṣe Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn Wọn si ń ta ohun ìní àti ẹrù wọn, wọn sì ń pín wọn fún olúkúlùkù, gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni tí í ṣe aláìní Wọ́n fi ọkàn kan dúró lójoojúmọ́ nínú tẹ́mpílì Wọ́n ń bu àkàrà ní ilé wọn, wọn ń fi inú dídùn àti ọkàn òtítọ́ jẹ oúnjẹ wọn Wọ́n yín Ọlọ́run, wọn sì rí ojú rere lọ́dọ̀ ènìyàn gbogbo, Olúwa sí ń yàn kún wọn lójoojúmọ́, àwọn tí à ń gbàlà Kọjá Ní Makedóníà Àti Gíríkì Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ ṣí Makedóníà Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ pupọ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ Gíríkì Ó sì dúró níbẹ̀ ní osù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àtibá ọkọ̀-ojú-omi lọ sí Síríà, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedóníà padà lọ Sópátérù ará Béríà ọmọ Páríù sì bá a lọ dé Éṣíà àti Sékúńdù àti Gáíúṣì ará Dábè, àti Tìmótíù ará Éṣíà, Tíkíkù àti Tírófímù Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí tí lọ síwájú, wọ́n dúró dè wá ni Tíróáṣì Àwa sì síkọ̀ láti Fílípì lọ lẹ́yìn ọjọ àkàrà àìwú, a sì dé ọ̀dọ̀ wọn ní Tíróáṣì ni ijọ́ méje Ọjọ́ ìkínní ọ̀ṣẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Pọ́ọ̀lù sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ijọ́ kejì ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárin ọ̀gànjọ́ Fìtílà púpọ̀ sì wà ní iyàrá òkè náà, níbi tí a gbé péjọ sí Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Éútíkù sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára bí Pọ́ọ̀lù sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n lójú oorun, ó súbù láti òkè kẹ́ta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbà á mọ́ra, ó ní, Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu nítorí tí òun wà láàyè Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ́ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà bọ̀ láàyè, inú gbogbo wọn sì dún lọ́pọ̀lọpọ̀ Nígbà ti àwa sì ṣáájú, àwa sì ṣíkọ̀ lọ sì Ásósì, níbẹ̀ ni a ti lérò láti gba Pọ́ọ̀lù sínú ọkọ̀ nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó tí pinnu rẹ̀, òun tìkararẹ̀ ń fẹ́ bá ti ọ̀nà-ẹṣẹ̀ lọ Nígbà tí ó sì pàdé wa ní Ásósì, a gbà á sínú ọkọ̀, a sì wá sí Mítílénì Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ijọ́ kejì a dé ọ̀kánkán Kíósì ní ijọ́ kejì rẹ̀ a dé Sámósì, a sì dúró ní Tírógílíónì ni ijọ́ kéjì rẹ̀ a sì dé Mílétù Pọ́ọ̀lù ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀-ojú omi kọjá ṣí Éféṣù, nítorí ki ó má baà lo àkókò kankan ni Éṣíà nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣééṣe fún un láti wà ní Jerúsálémù lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sítì Ní àti Mílétù ni Pọ́ọ̀lù ti ránṣẹ́ sí Éféṣù, láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá ṣọ́dọ̀ rẹ̀ Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, Ẹ̀yin tìkarayín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé Éṣíà, bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù Bí èmí kò ti fà ṣẹ́yìn láti sọ ohunkohun tí ó ṣàǹfàànì fún un yín, àti láti máa kọ́ ọ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé Tí mo ń sọ fún àwọn Júù, àti fún àwọn Gíríkì pẹ̀lú, ní ti ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì Olúwa wa Ǹjẹ́ nsṣinsìn yìí, wò ó, ẹ̀mí mi ń fà sì Jerúsálémù, láìmọ̀ ohun tí yóò bá mi níbẹ̀ Bí kò ṣe bí Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń sọ ní ìlú gbogbo pé, ìdè àti ìyà ń bẹ fún mi Ṣùgbọn èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó sọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́-ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jésù Olúwa, láti máa ròyìn ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọ̀lọ́run Ǹjẹ́ nísìnsìn yìí, wò ó, èmi mọ̀ pé gbogbo yín, láàrin ẹni tí èmi tí ń kiri wàásù ìjọba Ọlọ́run, kì yóò rí ojú mi mọ́ Nítorí náà mo pè yín ṣe ẹlẹ́rìí lónìí yìí pé, ọrùn mi mọ́ kúró nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo Nítorí tí èmi kò fà ṣẹ́yìn láti ṣọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún un yin Ẹ kíyèsára yin, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábòójútó rẹ̀, láti máa tọ́jú ìjọ Ọlọ́run, tí ó tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rà Nítorí tí èmi mọ̀ pé, lẹ́yìn lílọ̀ mi, ìkookò búburú yóò wọ àárin yín, yóò sì tú agbo ká Láàrin ẹ̀yin tìkárayín ni àwọn ènìyàn yóò sì dìde, tí wọn yóò máa sọ̀rọ̀-òdì, láti fa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sẹ́yìn wọn Nítorí náà ẹ máa sọ́ra, ki ẹ sì máa rántí pé, fún ọdún mẹ́ta, èmi kò dẹ́kun láti máa fi omijé kìlọ̀ fún olúkúlùkù ní ọ̀sán àti ní òru Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ará, mo fi yín lé Ọlọ́run lọ́wọ́ àti ọ̀rọ̀ oore-ọfẹ́ rẹ̀, tí ó lè gbé yín dúró, tí ó sì lè fún yín ní ìní láàrin gbogbo àwọn tí a sọ di mímọ́ Èmí kò ṣe ojúkòkòrò fàdákà, tàbí wúrà, tàbí aṣọ ẹnikẹ́ni Ẹ̀yin tìkárayín ṣáà mọ̀ pé, ọwọ́ mi wọ̀nyí ni mo fi ṣiṣẹ́ láti fi pèsè fún àìní mi, àti tí àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa, bí òun tìkararẹ̀ tí wí pé, láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ   Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà Gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù lọ́rùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu Inú wọn sì bàjẹ́ jùlọ fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé, wọn kì yóò rí ojú òun mọ́, wọ́n sì sìn ín títí dé inú ọkọ̀ Sí Jerúsálémù Lẹ́yìn tí àwa ti kúrò lọ́dọ̀ wọn, tí a sì ṣíkọ̀, àwa bá ọ̀nà wa lọ tàrà sí Kúúsì Ní ijọ́ kéjì a sì lọ sí Ródésì, àti gba ibẹ̀ lọ sí Pátarà A rí ọkọ̀ ojú-omi kan tí ń rékọ́ja lọ sí Fonísíà, a wọ inú ọkọ̀ náà, a sì síkọ̀ Nígbà tí àwa sì ń wo Sáípúrọ́sì lókèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Síríà, a sì gúnlẹ̀ ni Tírè nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù ṣílẹ̀ Nígbà tí a sì ti rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níbẹ̀, a dúró ní ọ̀dọ̀ wọn níbẹ̀ fún ijọ́ méje àwọn ẹni tí ó ti ipá Ẹ̀mí wí fún Pọ́ọ̀lù pé, kí ó má ṣe lọ sí Jerúsálémù Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà Nígbà tí a sì ti dágbére fún ara wa, a bọ́ sí ọkọ̀ bẹ́ẹ̀ ni àwọn sì padà lọ sí ilé wọn Nígbà tí a sì ti parí àjò wa láti Tírè, àwa dé Pítólémáì nígbà ti a sì kí àwọn ará, a sì bá wọn gbé ní ijọ́ kan Ní ijọ́ kejì a lọ kúrò, a sì wá sí Kesaríà nígbà tí á sì wọ ilé Fílípì ajíhìnrere tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méje àwa sì wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀ Ọkùnrin yìí sì ní ọmọbìnrin mẹ́rin, wúndíá, tí wọ́n máa ń sọtẹ́lẹ̀ Bí a sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, wòlíì kan tí Jùdíà sọ̀kalẹ̀ wá, tí a ń pè ní Ágábù Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Pọ́ọ̀lù, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹṣẹ̀, ó sì wí pé, Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerúsálémù yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fí i lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́   Nígbà tí a sì tí gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, àti àwa, àti àwọn ará ibẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe gòkè lọ ṣí Jerúsálémù Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù dàhun wí pé, Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi nítorí èmí tí múra tan, kì í se fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerúsálémù, nítorí orúkọ Jésù Olúwa Nígbà tí a kò lè pa á ní ọkàn dà, a dákẹ́ wí pé, Ìfẹ́ tí Olúwa ni kí ó ṣe! Lẹ́yìn ijọ́ wọ̀nyí, a palẹ̀mọ́, a sì gòkè lọ sí Jerúsálémù Nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti Kéṣáríà bá wa lọ, wọ́n sì mú wa lọ sí ilé Múnásónì ọmọ-ẹ̀yìn àtijọ́ kan ara Sàìpúrọ́sì, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa óò dé sí Nígbà tí a sì dé Jerúsálémù, àwọn arákùnrin sì fi ayọ̀ gbà wá, Ní ijọ́ kejì, a bá Pọ́ọ̀lù lọ sọ́dọ̀ Jákọ́bù gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀ Nígbà tí ó sì kí wọn tan, ó ròyìn lẹsẹẹsẹ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe láàrin àwọn aláìkọlà nípa iṣẹ́-ìránṣẹ́ rẹ̀ Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin Wọ́n sì ti ròyìn rẹ̀ fún wọn pé, ìwọ ń kọ́ gbogbo àwọn Júù tí ó wà láàrin àwọn aláìkọlà pé, kí wọn kọ Mósè sílẹ̀, ó ń wí fún wọn pé kí wọn má ṣe kọ àwọn ọmọ wọn ní ilà mọ́, kí wọn má sì ṣe rìn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn Ǹjẹ́ èwo ni ṣíṣe Ìjọ kò lè ṣàìmá pejọ pọ̀ dájúdájú wọn óò gbọ́ pé, ìwọ dé Ǹjẹ́ èyí tí àwa ó wí fún ọ yìí ni kí o ṣe Àwa ni ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́ Àwọn ni kí ìwọ mú, ki o sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn kí ó sì san owó láti fá irun orí wọn gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, kò sì òtítọ́ kan nínú ohun tí wọ́n gbọ́ sí ọ àti pé, ìwọ tìkararẹ ń rìn dédé, ìwọ sì ń pa òfin Mósè mọ́ Ṣùgbọ́n ní ti àwọn aláìkọlà tí ó gbàgbọ́, àwa tí kọ̀wé, a sì ti pinnu rẹ̀ pé, kí wọn pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀jẹ̀ àti ohun ìlọ́lọ́rùn pa, àti àgbérè Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù mú àwọn ọkùnrin náà ní ijọ́ kéjì ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, ó sì wọ inú tẹ́ḿpílì lọ, láti sọ ìgbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ náà yóò pé tí a ó sì fi ọrẹ lélẹ̀ fún olukùlùkù wọn Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Éṣíà wá rí i ni tẹ́ḿpílì, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un Wọ́n ń kígbe wí pé, Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbà wá Èyí ni ọkùnrin náà tí ń kọ́ gbogbo ènìyàn níbi gbogbo lòdì sí àwọn èniyan, àti sí òfin, àti sí ibí yìí àti pẹ́lú ó sì mú àwọn ará Gíríkì wá sí tẹ́ḿpílì, ó sì tí ba ibi mímọ́ yìí jẹ́ Nítorí wọ́n tí rí Tírófímù ará Éfésù pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú, ẹni tí wọ́n ṣe bí Pọ́ọ̀lù mú wá sínú tẹ́ḿpílì Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdo, àwọn ènìyàn sì súré jọ wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹ́ḿpílì lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerúsálémù dàrú Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Pọ́ọ̀lù Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é ó sì bèèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà-ipá àwọn ènìyàn Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, Mú un kúrò! Bí wọ́n sì tí fẹ́rẹ̀ mú Pọ́ọ̀lù wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó wí fún olórí-ogun pé, Èmi ha lè bá ọ sọ̀rọ̀ bí Ó sì dáhùn wí pé, Ìwọ mọ èdè Gíríkì bí Ìwọ ha kọ ní ara Íjíbítì náà, tí ó ṣọ̀tẹ̀ ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ti ó sì ti mú ẹgbàajì ọkùnrin nínú àwọn tí í ṣe apànìyàn lẹ́yìn lọ ṣí ijù Ṣùgbọ̀n Pọ́ọ̀lù sì wí pé, Júù ní èmi jẹ́, ará Tásọ́sì ilú Kílíkíà, tí kì í ṣe ìlú yẹpẹrẹ kan, èmi ṣí bẹ̀ ọ, fún mi ní ààyè láti bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ̀rọ̀! Nígbà tí ó sì tí fún un ní ààyè, Pọ́ọ̀lù dúró lórí àtẹ̀gùn, ó sì juwọ́ sí àwọn ènìyàn Nígbà tí wọ́n sì dákẹ́rọ́rọ́, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù, wí pé Pọ́ọ̀lù Ọmọ Ìbílẹ̀ Róòmu Ẹ̀yin ará àti baba, ẹ gbọ́ tí ẹnu mi nísinsìnyìí Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ni èdè Árámáíkì, wọ́n túbọ̀ dákẹ́ jẹ́ẹ́ Nígbà náà ni ó wí pé Júù ni èmi í ṣe, a bí mi ni Tásọ́sì ìlú kan ní Kílíkíà, ṣùgbọ́n tí a tọ́ mi dàgbà ni ìlú yìí Ní abẹ́ ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì ni a sì gbé kọ́ mi ní òfin àwọn baba wa, tí mo sì jẹ́ onítara fún Ọlọ́run àní gẹ́gẹ́ bí gbogbo yin tí rí ni òní Mo sì ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn tí ń tọ ọ̀nà yìí dé ojú ikú wọn, mo dè tọkùnrin àtobìnrin wọ́n, mo sì fi wọ́n sínú túbú, àní bí olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo àjọ àwọn alàgbà tí lè jẹ́ mi ní ẹ̀rí Mo tilẹ̀ gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakùnrin wọn ní Dámásíkù láti mú àwọn tí ó wà níbẹ̀ ní dídè wá sí Jerúsálémù, láti jẹ wọ́n níyà Bí èmi tí súnmọ́ etí Dámásíkù níwọ̀n ọjọ́kanrí, lójijì ìmọ́lẹ̀ ńlá láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí mi ká Mo sì subú lulẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan tí ó wí fún mi pé, Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi Mo sì béèrè pé, Ta ni ìwọ́, Olúwa Ó sì dá mi lóhùn pé, Èmi ni Jésù tí Násárétì, ẹni tí ìwọ́ ń ṣe inúnibíni sí Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi rí ìmọ́lẹ̀ náà nítòótọ́, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀ Mo sí béèrè pé, Kín ni kí èmí kí ó ṣe, Olúwa Olúwa sì wí fún mi pé, Dìde, kí o sì lọ sí Dámásíkù níbẹ̀ ni a ó sì ti sọ ohun gbogbo fún ọ tí a yàn fún ọ láti ṣe Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi fà mí lọ́wọ́ wọ Dámásíkù lọ nítorí tí èmi kò lè ríran nítorí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ náà ti fọ́ mi ní ojú Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Ananáyà tọ̀ mí wá, ẹni tó jẹ́ olùfọkànṣìn ti òfin, tí ó sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn Júù tí ó ń gbé ibẹ̀ Ó sì dúró tì mí, ó sì wí fún mi pé, Arákùnrin Ṣọ́ọ̀lù, gba ìríran! Ní ẹsẹ̀ kan náà, mo sì sí ojú sí òkè mo sì lè rí i Nígbà náà ni ó wí pé Ọlọ́run àwọn baba wa ti yàn ọ́ láti mọ ìfẹ́ rẹ̀, àti láti ri Ẹni Òdodo náà, àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu rẹ̀ Ìwọ yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn, nínú ohun tí ìwọ tí rí tí ìwọ sì ti gbọ́ Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, kín ni ìwọ ń dúró dè Dìde, kí a sì bamitíìsì rẹ̀, kí ó sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù, kí ó sì máa pé orúkọ rẹ̀ Nígbà tí mo padà wá sí Jerúsálémù tí mo ǹ gbàdúrà ní tẹ́ḿpílì, mo bọ́ sí ojúran, mo sì rí Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ fún mi pé, Kíá! Jáde kúrò ní Jerúsálémù kán-kán, nítorí wọn kì yóò gba ẹ̀rí rẹ nípa mi gbọ́ Èmi sì wí pé, Olúwa, àwọn ènìyàn wọ̀nyí pàápàá mọ̀ pé èmi ti lọ láti inú sínágọ́gù kan sí èkejì láti máa sọ wọ́n sínú túbú àti láti máa lu àwọn tí ó gbà ọ́ gbọ́ Nígbà tí a sì ta ẹ̀jẹ̀ Sítéfánù ẹlẹ́ríì rẹ sílẹ̀, èmi náà pẹ̀lú dúró níbẹ̀, mo sì ní ohùn sí ikú rẹ̀, mo sì ń se ìtọ́jú aṣọ àwọn ẹni tí ó pa á Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, Máa lọ nítorí èmi ó rán ọ sí àwọn aláìkọlà lókèèrè réré   Wọ́n sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù títí tí ó fi sọ ọ̀rọ̀ yìí Nígbà yìí ni wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì kígbe wí pé, Ẹ mu ẹni yìí kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láàyè! Bí wọ́n sì ti ń kígbe, tí wọ́n sì ń jú aṣọ wọn káàkiri, tí wọ́n ń ku eruku sí ojú ọ̀run, olórí ogun pàṣẹ pé kí a mú Pọ́ọ̀lù wá sínú àgọ́ àwọn ológun Ó sì pàṣẹ kí wọ́n ó lù ú, kí wọn fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, kí òun baà lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lé e lórí bẹ́ẹ̀ Bí wọ́n sí tí fi okùn-ọṣán dè é, Pọ́ọ̀lù bí balógun ọ̀rún tí ó dúró tì í pé, Ó ha tọ́ fún yín láti na ẹni tí i ṣe ará Róòmù ni àìdálẹ́bi bí Nígbà tí balógun ọ̀rún sì gbọ́ èyí, ó lọ wí fún olórí-ogun pé, Kín ni ó fẹ́ ṣe yìí nítorí ọkùnrin yìí ará Róòmù ní i ṣe Olórí-ogun sì dé, ó sì bí Pọ́ọ̀lù pé, Sọ fún mi, ará Róòmù ni ìwọ jẹ́ bí Ó sì wí pé, Bẹ́ẹ̀ ni Olórí-Ogun sì dáhùn wí pé, Owó púpọ̀ ni mo fi ra ọlá ìbílẹ̀ yìí Pọ́ọ̀lù wí pé, Ṣùgbọn a bí mi sínú rẹ̀ ni Nítorí náà àwọn tí ó múra láti fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ lójúkan náà Ọlórí-ogun pẹ̀lú sì bẹ̀rù nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ní Pọ́ọ̀lù i ṣe, àti nítorí ó tí dè é Ní ijọ́ kéjì, nítorí tí olórí-ogun fẹ́ mọ̀ dájúdájú ohun tí àwọn Júù ń fi Pọ́ọ̀lù sùn sí, ó túu sílẹ̀, ó pàṣẹ kí àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ, nígbà náà ni ó mú Pọ́ọ̀lù sọ̀kalẹ̀, ó sì mú un dúró ní wájú wọn Ìdìtẹ̀ Láti Pa Pọ́ọ̀lù Pọ́ọ̀lù tẹjúmọ́ ìgbìmọ̀, ó sì wí pé, Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi tí ń fi gbogbo ẹ̀rí ọkàn rere lo ayé mi níwájú Ọlọ́run títí fí di òní yìí Nígbà yìí ni Ananíyà olórí àlùfáà pàṣẹ fún àwọn tí ó dúró tí Pọ́ọ̀lù pé, kí wọn ó gbá a lẹ́nu Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù wí fún un pé, Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ogiri tí a kùn lẹ́fun ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan-an alára rú òfin nípa pípaṣẹ pé kí a lù mí! Àwọn tí ó dúró tì Pọ́ọ̀lù sì wí pé, Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run Pọ́ọ̀lù sì dá wọn lóhùn pé, Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni nítorí a tí kọ ọ́ pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú   Ṣùgbọ́n nígbà tí Pọ́ọ̀lù sàkíyèsí pé, apákan wọn jẹ́ Sádúsì, apákan sì jẹ́ Farisí, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, Ẹ̀yin arákùnrin mi, Èmi jẹ́ Farisí, ọmọ Farisí sì ni èmi mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú Nígbà tí ó sì tí wí èyí, ìyapa dé láàrin àwọn Farisí àti àwọn Sádúsì àjọ sì pín sì méjì Nítorí tí àwọn Sádúsì wí pé, kò sì àjíǹde, tàbí ańgẹ́lì, tàbí ẹ̀mí ṣùgbọ́n àwọn Farisí jẹ́wọ́ méjèèjì Ó sì di ariwo ńlá, nínú àwọn olùkọ́ òfin tí ó wà ni apá tí àwọn Farisí dìde, wọ́n ń jà, wí pé, Àwa kò rí ohun búburú kan lára ọkùnrin yìí, wọ́n wí àwa kò sì mọ̀ nítòótọ́ bí áńgẹ́lì kan tàbí ẹ̀mí kan ń baà sọ̀rọ̀ Nígbà tí ìyapa sì di ńlá, tí olórí ogun bẹ̀rù kí Pọ́ọ̀lù má baà di fífàya lọ́wọ́ wọn, ó pàṣẹ pé ki àwọn ọmọ-ogun sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ipá mú un kúrò láàrin wọn, kí wọn sì mú un wá sínú àgọ́ àwọn ológun Ní òru ijọ́ náà Olúwa dúró tì Pọ́ọ̀lù, ó wí pé, Mú ọkàn le! Bí ìwọ ti jẹ́rìí fún mi ní Jerúsálémù, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò lè ṣàìjẹ́rìí ni Róòmù pẹ̀lú Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Júù kan dìtẹ̀, wọ́n fi ara wọn bú pé, awọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ní àwọn kì yóò mú títí àwọn ó fi pa Pọ́ọ̀lù Àwọn tí ó dìtẹ̀ yìí sì ju ogójì ènìyàn lọ Wọ́n sì tọ olórí àwọn àlùfáà àti àwọn alàgbà lọ, wọn sì wí pé, Àwa tí fi ara wa sínú ìdè ìbúra pé, a kì yóò tọ́ oúnjẹ kan wò títí àwa ó fi pa Pọ́ọ̀lù Ǹjẹ́ nísinsìn yìí kí ẹ̀yin pẹ̀lú àjọ ìgbìmọ̀ wí fún olórí-ogun, kí ó mú un sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá, bí ẹni pé ẹ̀yin ń fẹ́ wádìí ọ̀ràn rẹ̀ dájúdájú Kí ó tó súnmọ́ tòòsí, àwa ó ti múra láti pa á Nígbà tí ọmọ arabínrin Pọ́ọ̀lù sí gbúrò ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Pọ́ọ̀lù Pọ́ọ̀lù sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí-ogun lọ nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí-ogun Balógun ọ̀rún náà wí pé, Pọ́ọ̀lù òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sí bẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ Olórí-ogun fà á lọ́wọ́, ó sì lọ si apá kan, ó sì bi í léèrè níkọ̀kọ̀ pé, Kín ni ohun tí ìwọ ní sọ fún mi Ó sì wí pé, Àwọn Júù fi ìmọ̀ sọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Pọ́ọ̀lù sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbimọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ bèèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀ Nítorí náà má ṣe gbọ́ ti wọn nítorí àwọn tí ó dènà dè é nínú wọn ju ogójì ọkùnrin lọ, tí wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kì yóò mu títí àwọn o fi pa á Wọ́n sì ti múra tan nísinsìn yìí, wọ́n ń retí ìdáhùn lọ́dọ̀ rẹ Nígbà náà ni olórí ogun fi ọmọ náà sílẹ̀ láti lọ, ó sí kìlọ̀ fún un pé, Má ṣe wí fún ẹnìkan pé, ìwọ fí nǹkan wọ̀nyí hàn mi Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ ṣí Kesaríà, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹ́ta òru Ó sì wí pé, kí wọn pèṣè ẹranko, kí wọ́n gbé Pọ́ọ̀lù gùn ún kí wọ́n sì lè mú un dé ọ̀dọ̀ Fẹ́líkísì baálẹ̀ ní àlàáfíà Ó sì kọ ìwé kan báyìí pé Kíláúdíù Lísíà, Sí Fẹ́líkísì baálẹ̀ ọlọ́lá jùlọ Àlàáfíà Àwọn Júù mú ọkùnrin yìí, wọ́n sì ń pète láti pa á nígbà náà ni mo dé pẹ̀lú ogun, mo sì gbà á lọ́wọ́ wọn nígbà tí mo gbọ́ pé ará Róòmù ni í ṣe Nígbà tí mo sì ń fẹ́ mọ ìdí ọ̀ràn tí wọn fi ẹ̀sùn kàn án sí, mo mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí àjọ ìgbìmọ̀ wọn Ẹni tí mo rí pé, wọ́n fisùn nítorí ọ̀ràn òfin wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọ̀ràn ohun kan tí ó tọ́ sí ikú àti sí ẹ̀wọ̀n Nígbà tí a sì tí jí i sọ fún mi pé, wọn yóò dènà de ọkùnrin náà, mo rán an sí ọ lọ́gán, mo sì pàṣẹ fún àwọn olùfisùn rẹ̀ pẹ̀lú, láti sọ ohun tí wọ́n bá rí wí sí i níwájú rẹ̀ Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gba Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì mú un lóru lọ si Áńtírípátírì, gẹ́gẹ́ bí a tí pàṣẹ fún wọn Ní ọjọ́ kejì wọ́n sì fi àwọn ẹlẹ́ṣin sílẹ̀ láti máa bá a lọ, àwọn sì padà wá sínú àgọ́ àwọn ológun Nígbà tí wọ́n dé Kesaríà, tí wọ́n sí fi ìwé fún baalẹ́, wọ́n mú Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú wá ṣíwájú rẹ̀ Nígbà tí ó sì ti ka ìwé náà, ó bèèrè pé agbégbé ìlú wo ni tirẹ̀ Nígbà tí ó sì gbọ́ pé ará Kílíkíà ni Ó ní, Èmi yóò gbọ ẹjọ́ rẹ, nígbà tí àwọn olùfiṣùn rẹ pẹ̀lú bá dé Ó sì paṣẹ pé kí wọn pa Pọ́ọ̀lù mọ́ ní abẹ́ àmójútó àwọn olùsọ́ ní gbọ̀ngán-ídájọ́ ààfin Hẹ́rọ́dù Ìpèlẹ́jọ Níwájú Fẹ́líkísì Lẹ́yìn ọjọ́ márùn-ún Ananíyà olórí àlúfáà náà sọkalẹ̀ lọ pẹ̀lú àwọn alàgbà àti ẹnìkan, Tátúlù agbẹjọ́rò, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù fún baálẹ̀ Nígbà tí a sí tí pè Pọ́ọ̀lù jáde, Tátúlù gbé ẹjọ́ rẹ̀ kalẹ̀ níwájú Fẹ́líkísì ó wí pé Àwa ti wà ní àlàáfíà ní abẹ́ ìjọba rẹ lá ìgbà pípẹ́ wá, àti pé ìfojúsù rẹ ti mú àyípadà rere bá orílẹ̀-èdè yìí Ní ibi gbogbo àti ní ọ̀nà gbogbo, Fẹ́líkísì ọlọ́lá jùlọ, ní àwa ń tẹ́wọ́gbà á pẹ̀lú ọpẹ́ gbogbo Ṣùgbọ́n kí èmi má baa dá ọ dúró pẹ́ títí, mo bẹ̀ ọ́ kí o fi ìyọ́nú rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ díẹ̀ lẹ́nu wa Nítorí àwa rí ọkùnrin yìí, ó jẹ́ oníjàngbàn ènìyàn, ẹni tí ó ń dá rúkèrúdò ṣílẹ̀ láàrin gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní gbogbo ayé Òun ni aṣáájú búburú kan nínú ẹ̀yà àwọn Násárénè Ẹni tí ó gbìyànjú láti ba tẹ́ḿpílì jẹ́ ṣùgbọ́n àwa gbá a mú àwa sí fẹ báa ṣe ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin wa Ṣùgbọ́n Lísíà olórí ogun dé, ó fì agbára ńlá gbà á lọ́wọ́ wa Nígbà tí ìwọ fúnrarẹ bá wádìí ọ̀rọ̀ fínní fínni lẹ́nu rẹ̀, ìwọ ó lè ní òye òtítọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí àwa fi ẹ̀ṣùn rẹ̀ kàn án Àwọn Júù pẹ̀lú sì fi ohùn sí i wí pé, ní òtítọ́ bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí Nígbà tí baálẹ̀ ṣẹ́wọ́ sì i pé kí ó sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù sì dáhùn wí pe Bí mo tí mọ̀ pé láti ọdún mélòó yìí wá, ní ìwọ tí ṣe onídájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, nítorí náà mo fi tayọ̀ tayọ̀ wí tí ẹnu mi Ìwọ pẹ̀lú sì ní òye rẹ̀ pé, ìjejìlá ni mo lọ sí Jerúsálémù láti lọ jọ́sìn Bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùfisùn mi kò rí mi kí ń máa bá ẹnìkẹ́ni jiyàn nínú téḿpílì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ru àwọn ènìyàn sókè nínú ṣínágọ́gù tàbí ní ibikíbi nínú ìlú Bẹ́ẹ̀ ní wọ́n kò lè fi ìdí ẹ̀sùn múlẹ̀ níwájú rẹ, èyí tí wọn fi mí sùn sí nísinsìn yìí Ṣùgbọ́n, èmí jẹ́wọ́ fún ọ pé, èmi ń sin Ọlọ́run àwọn baba wa gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń tẹ̀le ọ̀nà tí wọ́n ń pè ni ìyapa-ìsìn Èmi ń gbá gbogbo nǹkan ti a kọ sínú ìwé òfin gbọ́, àti tí a kọ sínú ìwé àwọn wòlíì, mo sí ní ìrètí kan náà nínú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn tìkaráwọn jẹ́wọ́ pẹ̀lú, wí pé àjíǹde òkú ń bọ̀, àti tí olóòtọ́, àti tí aláìsòótọ́ Nínú èyí ni èmi sì ti ń gbìyànjú láti ní ẹ̀rí-ọkàn tí kò lẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, àti sí ènìyàn nígbà gbogbo Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdun púpọ̀, mo wá sí Jerúsálẹ́mù láti mu ẹ̀bún wá fún àwọn ẹ̀nìyàn mi fún aláìní àti láti fi ọrẹ lélẹ̀ Nínú ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí, wọ́n rí mí nínú iyẹ̀wù tẹ́ḿpílì, bí mo ti ń parí ètò ìwẹ́nú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ní àárin àwùjọ ènìyàn, tàbí pẹ̀lú ariwo Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan láti ẹkùn Éṣíà wà níbẹ̀, àwọn tí ì bá wà níhìn-ín yìí níwájú rẹ, kí wọn já mi nírọ́, bí wọ́n bá ní ohunkohun sí mi Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tíkarawọn sọ iṣẹ́ búburú tí wọ́n rí lọ́wọ́ mi, nígbà tí mo dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀ Bí kò ṣe tí gbolóhùn kan yìí, tí mo kégbe rẹ̀ ṣíta nígbà tí mo dúró láàrin wọn Èyí ni tìtorí àjíǹde òkú ni a ṣe ba mi wíjọ́ lọ́dọ̀ yín lóni yìí!  Nígbà tí Fẹ́líkísì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí òye sà yè e ní àyétan nípa ọ̀nà náà ó tú wọn ká ná, ó ní, Nígbà tí Lísíà olórí ogun bá ṣọ̀kalẹ̀ wá, èmi ó wádìí ọ̀ràn yín dájú Ó sì pàṣẹ fún balógun ọ̀run kan kí ó fi Pọ́ọ̀lù sí a bẹ́ ìsọ́, ṣùgbọ́n kí ó fún un ní ààyè, àti pé kí ó má ṣe dá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan Fẹ́líkísì pẹ̀lú Dírúsílà ìyàwó rẹ̀ dé, obìrin tí í ṣe Júù Ó ranṣẹ́ pé Pọ́ọ̀lù, ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Jésù Bí Pọ́ọ̀lù sì tí ń sọ àsọyé nípa tí òdodo àti àìrékọjá àti ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Fẹ́líkísì, ó dáhùn wí pé, Èyí tí o sọ nì tó ná! Máa lọ nísinsìn yìí ná Nígbà tí mo bá sì ní àkókò tí ó wọ̀, èmi ó ránṣẹ́ pè ọ́ Ní àkókó yìí kan náà, ó ń retí pẹ̀lú pé Pọ́ọ̀lù yóò mú owó-ẹ̀yìn wá fún òun, kí òun baà lè dá a sílẹ̀ nítorí náà, a sì máa ránṣẹ́ sì í nígbàkúgbà, a máa bá a sọ̀rọ̀ Lẹ́yìn ọdun méjì, Póríkíúsì Fẹ́sítúsì rọ́pò Fẹ́líkísì Fẹ́líkísì ṣí ń fẹ́ se ojú rere fún àwọn Júù, ó fí Pọ́ọ̀lù sìlẹ́ nínú túbú Ìjẹ́jọ́ Níwájú Fẹ́sítọ̀ọ́sì Lẹ́yìn ọjọ́ méta tí ó dé sí ilẹ̀ náà, Fésítúsì gòkè láti Kesaríà lọ sì Jerúsálémù, ní ibi tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn pàtàkì nínú àwọn Júù ti gbé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù wá síwájú rẹ̀ Wọ́n tọrọ lọ́wọ́ Fẹ́sítúsì, kí ó bá le se ojúrere fuń wọn, kí ó bá à lè jẹ́ kí wọn mú Pọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálémù, wọn ń gbìmọ̀ láti dènà dè é, kí wọn sì pa á ní ọ̀nà Ṣùgbọ́n Fẹ́sítúsì dáhùn pé, A pa Pọ́ọ̀lù mọ́ ní Kesaríà, àti pé òun tíkara òun ń múra àti padà lọ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí Ẹ jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn olórí yín bá mi sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ìdí ẹ̀sùn tí ẹ fi sun ọkùnrin náà múlẹ̀ níbẹ̀, bí ó bá ní ohun búburú kan tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ Lẹ́yìn tí ó sì ti gbé níwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá pẹ̀lú wọn, ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sì Kesaríà, ni ọjọ́ kéjì ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì pàṣẹ pé ki a mú Pọ́ọ̀lù wá síwájú òun Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerúsálémù ṣọ̀kalẹ̀ wá dúró yì í ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Pọ́ọ̀lù lọ́rùn, tí wọn kò lè làdí rẹ̀ Pọ́ọ̀lù si wí tí ẹnu rẹ̀ pé, Èmi kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ kan sì òfin àwọn Júù, tàbí tẹ́ḿpílì, tàbí sí Késárì Ṣùgbọ́n Fẹ́sítúsì ń fẹ́ láti ní ojúrere lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó sì dá Pọ́ọ̀lù lóhùn, wí pe, Ìwọ ń fẹ́ gòkè lọ sì Jerúsálémù, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ níwájú mi bí Pọ́ọ̀lù sì wí pé, Mo dúró níwájú ìtẹ́-ìdájọ́ Késárì níbi tí ó yẹ kí a ṣe ẹjọ́ mí èmi kò ṣẹ àwọn Júù, bí ìwọ pẹ̀lú ti mọ̀ dájú Ǹjẹ́ bí mo bá ṣẹ̀, tí mo sí ṣe ohun kan tí ó yẹ fún ikú, èmi kò kọ̀ láti kú ṣùgbọn bí kò bá sí otítọ́ kan nínú ẹ̀sùn tí àwọn Júù yìí fi mi sùn sí, ẹnìkan kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fà mí lé wọn lọ́wọ́ Mo fí ọ̀ràn mi lọ Késárì Lẹ́yìn tí Fẹ́sítúsì ti bá àjọ ìgbìmọ̀ sọ̀rọ̀, ó dáhùn pé, Ìwọ ti fi ọ̀ràn rẹ lọ Késárì Ní ọ̀dọ̀ Késárì ni ìwọ ó lọ! Lẹ́yìn ijọ́ mélòó kan, Àgírípà ọba, àti Béníkè sọ̀kalẹ̀ wá sì Kesaríà láti kí Fẹ́sítúsì Bí wọ́n sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, Fẹ́sítúsì mú ọ̀ràn Pọ́ọ̀lù wá síwájú ọba, wí pé, Fẹ́líkísì fi ọkùnrin kan ṣílẹ̀ nínú túbú Ẹni tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn Júù fi sùn nígbà tí mo wà ni Jerúsálémù, wọ́n ń fẹ́ kí èmi ó dá a lẹ́bi ikú Àwọn ẹni tí mo sì dá lóhùn pé, kì í ṣe àṣà àwọn ará Róòmù láti dá ẹnìkẹ́ni lẹ́bí, kí ẹni tí a fiṣùn náà tó ko àwọn olùfisùn rẹ̀ lójú, láti lè ri àyè wí tí ẹnu rẹ̀, nítorí ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn, Nítorí náà nígbà tí wọ́n jùmọ̀ wá sí ìhín yìí, èmi kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rara, níjọ́ kéjì mo jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wá Nígbà tí àwọn olùfiṣùn náa dìde, wọn kò ka ọ̀ràn búburú irú èyí tí mo rò sí i lọ́rùn Ṣùgbọ́n wọ́n ní ọ̀ràn kan sí i, ní ti ìsìn wọn, àti ní ti Jésù kan tí o tí kú, tí Pọ́ọ̀lù tẹnumọ́ pé ó wà láàyè Bí èmi kò sì tí mọ̀ bí a tí ń se ìwàdìí nǹkan wọ̀nyí, mo bí i lere pé ṣe ó ń fẹ́ lọ sì Jerúsálémù, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ Ṣùgbọ̀n nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi ọ̀ràn rẹ lọ Ọ̀gọ́sítù, pé kí a pa òun mọ́ fún ìdájọ́ rẹ̀, mo pàṣẹ pé kí a pa á mọ́ títí èmi o fi lè rán an lọ sọ́dọ̀ Késárì Àgírípà sí wí fún Fésítúsì pé, Èmi pẹ̀lú fẹ́ láti gbọ ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà tìkááramì, Ó sì wí pé, Ní ọ̀la ìwọ ó gbọ́ ọ Ní ọjọ́ kejì, tí Àgírípà àti Báníkè wọ ilé ẹjọ́ ti àwọn ti ẹ̀sọ́ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn ńlá ní ìlú, Fẹ́sítúsì pàṣẹ, wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù jáde Fẹ́sítúsì sì wí pé, Àgírípà Ọba, àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn tí ó wà níhìn pẹ̀lú wa, ẹ̀yin rí ọkùnrin yìí, nítorí ẹni tí gbogbo ìjọ àwọn Júù tí fi ẹ̀bẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ mi ni Jerúsálémù àti Kesaríà níhìn yìí, tí wọ́n ń kígbe pé, kò yẹ fún un láti wà láàyè mọ́ Ṣùgbọ́n èmi rí i pé, kò se ohun kan tí ó yẹ sí ikú, bí òun tìkárarẹ̀ sí tí fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Aúgọ́sítù, mo tí pinnu láti rán an lọ Ṣùgbọ́n èmi kò ri ohun kan dájúdájú láti kọ̀wé sí olúwa mi Nítorí náà ni mo ṣe mú un jáde wá ṣíwájú yín, àní ṣíwájú rẹ ọba Àgírípà, kí o fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí a ba tí se wádìí rẹ̀, èmi yóò lè rí ohun tí èmi yóò kọ Nítorí tí kò tọ́ ní ojú mi láti rán òǹdè, kí a má sì sọ ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn Àgírípà sì wí fún Pọ́ọ̀lù pé, A fún ọ láàyè láti sọ tí ẹnu rẹ Nígbà náà ní Pọ́ọ̀lù ná ọwọ́, ó sì sọ ti ẹnu rẹ pé Àgírípà ọba, inú èmi tìkárami dùn nítorí tí èmi yóò wí ti ẹnu mi lónìí níwájú rẹ, ní ti gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn Júù fi mi sùn, pàápàá bí ìwọ tí mọ gbogbo àṣà àti ọ̀ràn tí ń bẹ́ láàrin àwọn Júù dájúdájú Nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́ kí ìwọ fí sùúrù tẹ́tí gbọ́ tèmi Àwọn Júù mọ irú ìgbé ayé tí mo ń gbé láti ìgbà èwe mi, láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi ní orílẹ̀-èdè mi àti ní Jerúsálémù Nítorí wọ́n mọ̀ mi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́rìí sí i, wí pé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìsìn wa tí ó lè jùlọ, Farisí ni èmi Nísinsìn yìí nítorí ìrètí ìlérí tí Ọlọ́run tí ṣe fún àwọn baba wa ni mo ṣe dúró níhìn-ín fún ìdájọ́ Ìlérí èyí tí àwọn ẹ̀yà wa méjèèjìlá tí ń fi ìtara sin Ọlọ́run lọ́sàn-án àti lóru tí wọ́n ń retí àti rí ì gbà Ọba, n ítorí ìrètí yìí ni àwọn Júù ṣe ń fi mi sùn Èéṣe tí ẹ̀yin fi rò o sí ohun tí a kò lè gbàgbọ́ bí Ọlọ́run bá jí òkú dìde Èmi tilẹ̀ rò nínú ará mi nítòótọ́ pé, ó yẹ ki èmi ṣe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun lòdì sí orúkọ Jésù tí Násárétì Èyi ni mo sì ṣe ni Jerúsálémù Pẹ̀lú àṣẹ tí mo tí gba lọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, mo sọ àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mímọ́ sí inú túbú, nígbà tí wọ́n sí ń pa wọ́n, mo ní ohùn sí i Nígbà púpọ̀ ni mo ń fi ìyà jẹ wọ́n láti inú ṣínágọ́gù dé inú ṣínágọ́gù, mo ń fi tipá mú wọn láti sọ ọ̀rọ̀-òdì Mo sọ̀rọ̀ lòdì ṣí wọn gidigidi, kódà mo wá wọn lọ sí ìlú àjèjì láti ṣe inúnibíni sí wọn Nínú irú ìrìnàjò yìí ní mo ń bá lọ sí Dámásíkù pẹ̀lú ọlá àti àṣẹ ikọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà Ni ọ̀ṣángangan, ìwọ ọba, bí mo ti wà ní ojú ọ̀nà, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run wá, tí ó mọ́lẹ̀ ju òòrùn lọ, ó mọ́lẹ̀ yí mi ká, àti àwọn tí ń bá mi lọ sì àjò Gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn tí ń fọ sì mi ni èdè Hébérù pé, Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù! Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni ṣí mi Ohun ìrora ní fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún! Èmi sì wí pé, Ìwọ ta ni, Olúwa Olúwa sì wí pé, Èmi ni Jésù tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí Ṣùgbọ́n dìde, kí o sí fi ẹṣẹ̀ rẹ tẹlẹ̀ nítorí èyí ni mo ṣe farahàn ọ́ láti yàn ọ́ ní ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí, fún ohun wọ̀nyí tí ìwọ tí rí nípa mi, àti àwọn ohun tí èmi yóò fí ara hàn fún ọ Èmi yóò gbà ọ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ àti lọ́wọ́ àwọn Kèfèrì Èmi rán ọ ṣí wọn nísìnsìn yìí láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Sátanì ṣí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi Nítorí náà, Àgírípà ọba, èmi kò ṣe àìgbọ́ràn sì ìran ọ̀run náà Ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ sọ fún àwọn tí ó wà ní Dámásíkù, àti ní Jerúsálémù, àti já gbogbo ilẹ Jùdíà, àti fún àwọn Kèfèrì, kí wọn ronúpìwàdà, kí wọ́n sì yípadà sí Ọlọ́run, kí wọn máa ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ sì ìrònúpìwadà Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni àwọn Júù ṣe gbá mi mú nínú tẹ́ḿpílì, tí wọ́n sì ń fẹ́ pá mí Ṣùgbọ́n bí mo sì tí ri ìrànlọ́wọ́ gbà láti lọ́dọ̀ Ọlọ́run, mo dúró títí ó fí di òní, mo ń jẹ́rìí fún àti èwe àti àgbà, èmi kò sọ ohun mìíràn bí kò ṣe ohun tí àwọn wòlíì àti Móṣè tí wí pé, yóò ṣẹ Pé, Kírísítì yóò jìyà, àti pé Òun ni yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti jíǹde kúrò nínú òkú, Òun ni yóò sí kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti fún àwọn Kèfèrì Ní ìkóríta yìí Fẹ́sítúsì kọ dí àwíjàre Pọ́ọ̀lù, ó wí lóhùn rara pé, Pọ́ọ̀lù, orí rẹ dàrú ẹ̀kọ́ àkọ́jù rẹ ti dà ọ́ ní orí rú! Pọ́ọ̀lù da lóhùn wí pé, Orí mi kò dà rú, Fẹ́sítúsì ọlọ́lá jùlọ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ òye ni èmi ń sọ jáde Nítorí ọba mọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, níwájú ẹni tí èmi ń ṣọ̀rọ̀ ni àìbẹ̀rù nítorí mo gbàgbọ́ pé ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò pamọ́ fún un, nítorí tí a kò ṣe nǹkan yìí ní ìkọ̀kọ̀ Àgírípà ọba, ìwọ gba àwọn wòlíì gbọ́ bí Èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́ Àgírípà sì wí fún Pọ́ọ̀lù pé, Ǹjẹ́ ìwọ ró pé ìwọ́ fi àkókò díẹ̀ yìí sọ mí di Kírísítìẹ́nì Pọ́ọ̀lù sì dáhùn wí pé, Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí Nígbà tí ó sì sọ nǹkan wọ̀nyí tan, ọba dìde, àti baálẹ̀, àti Béníkè, àti àwọn tí o bá wọn jokòó Nígbà tí wọn wọ yẹ̀wù lọ, wọn bá ara wọn jíròrò, wọ́n sọ pé, Ọkùnrin yìí kò ṣe nǹkan kan tí ó yẹ sí ikú tàbí sì ẹ̀wọ̀n Àgírípà sì wí fún Fẹ́sítúsì pé, A bà dá ọkùnrin yìí ṣílẹ̀ bí ó bá ṣe pè kòì tíì fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Késárì Pọ́ọ̀lù Tàgbòkùn Ọkọ Sí Róòmù Bí a sì ti pinnu rẹ̀ pé kí a wọ ọkọ̀ lọ sí Ítalì, wọn fi Pọ́ọ̀lù àti àwọn òǹdè mìíràn lé balógun ọ̀rún kan lọ́wọ́, ti a ń pè ní Júlíọ́sì, ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Ọ̀gọ́sítúsì Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-okun Ádírámítíù kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí òkun Éṣíà, a ṣíkọ̀ Árísítakù, ará Makedóníà láti Tẹsalóníkà wà pẹ̀lú wa Ní ijọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sídónì Júlíọ́sì sì ṣe inú rere sì Pọ́ọ̀lù, ó sì fún un láàyè kí ó máa tọ àwọn ọrẹ̀ rẹ̀ lọ kí wọn le se ìtọ́jú rẹ̀ Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ níbẹ̀, a lọ lẹ́bá Kípírúsì, nítorí tí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì Nígbà tí a ré òkun Kílíkíà àti Paḿfílíà kọjá, a gúnlẹ̀ sí Mírà ti Líkíà Níbẹ̀ ni balogun ọ̀rún sì rí ọkọ̀-okun Alekisáńdírà kan, ti ń lọ sí Ítalì ó sì fi wa sínú rẹ̀ Nígbà tí a ń lọ jẹ́jẹ́ ní ọjọ́ púpọ̀, ti a fi agbára káká dé ọkánkán Nídúsì, àti nítorí tí afẹ́fẹ́ kò fún wa láàyè, a ba ẹ̀bá Kírétè lọ, lọ́kankán Sálímónì Nígbà tí a sì fi agbára káká kọjá rẹ̀, a dé ibi tí a ń pè ní Èbùté Yíyanjú, tí ó súnmọ́ ìlú Láséà Nígbà ti a sì ti sọ ọjọ́ púpọ̀ nù, àti pé ìrìn-àjò wa sì ti léwu gan-an nítorí nisinsinyìí ààwẹ̀ ti kọjá lọ, Pọ́ọ̀lù dá ìmọ̀ràn Ó sì wí fún wọn pé, Alàgbà, mo wòye pé ìṣíkọ̀ yìí yóò ní ewu, òfò púpọ̀ yóò sì wá, kì í ṣe kìkì ti ẹrù àti ti ọkọ̀, ṣùgbọ́n ti ọkàn wa pẹ̀lú Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún gba ti olórí ọkọ́ àti ti ọlọ́kọ̀ gbọ́, ju ohun wọ̀nyí tí Pọ́ọ̀lù wí lọ Àti nítorí pé èbúté náà kò rọrùn láti lo àkókò òtútù níbẹ̀, àwọn púpọ̀ sí dámọ̀ràn pé, kí a lọ kúrò níbẹ̀, bóyá wọn ó lè làkàkà dé Fóníkè, tí i ṣe èbúté Kírétè ti ó kọjú sí òsì ìwọ̀-oorùn, àti ọ̀tún ìwọ̀-oorùn, láti lo àkókò òtútù níbẹ̀ Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúsù sì ń fẹ́ jẹ́jẹ́, tí wọn ṣèbí ọwọ́ àwọn tẹ ohun tí wọn ń wá, wọ́n ṣíkọ̀, wọn ń pá ẹ̀bá Kírétè lọ Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjì ti a ń pè ni Éúrákúílò fẹ́ lù ú Nígbà ti ó sì ti gbé ọkọ̀-okun náà, ti kò sì lè dojúkọ ìjì yìí, a fi i sílẹ̀, ó ń gbá a lọ Nígbà tí ó sì gbá a lọ lábẹ́ erékùsù kan tí a ń pè Kíláúdà, ó di iṣẹ́ púpọ̀ kí a tó lè súnmọ́ ìgbàjà Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ́-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrin-dídẹ̀, wọn fi ìgbòkun sílẹ̀, bẹ́ẹ́ ni a sì ń gbá wa kiri Bí a sì ti ń ṣe làálàá gidigidi nínú ìjì náà, ni ijọ́ kejì wọn kó ẹrù-ọkọ̀ dà sí omi láti mú ọkọ̀ fẹ́rẹ̀ Ní ijọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn kó ohun-èlò ọkọ̀ dànù Nígbà tí òòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́ Nígbà tí wọ́n wà ní àìjẹun lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà náà Pọ́ọ̀lù dìde láàrin wọn, ó ní, Alàgbà, ẹ̀yin bá ti gbọ́ tèmi kí a má ṣe ṣíkọ̀ kúrò ní Kírétè, ewu àti òfò yìí kì ìbá ti bá wa Ǹjẹ̀ nísinsìn yìí mó gbà yín níyànjú, kí ẹ tújúká nítorí kí yóò sí ẹni tí yóò nù, bí kò ṣe ti ọkọ̀ Nítorí ańgẹ́lì Ọlọ́run, ẹni tí èmi jẹ́ tirẹ̀, àti ẹni ti èmi ń sìn, ó dúró tì mi ni òru àná Ó wí pé, Má bẹ̀rù, Pọ́ọ̀lù ìwọ kò lè ṣàìmá dúró níwájú Késárì Sì wò ó, Ọlọ́run ti fi gbogbo wọn ti ó bá ọ wọ ọkọ̀ pọ̀ fún ọ Ǹjẹ́ nítorí náà, alàgbà, ẹ dárayá nítorí mo gba Ọlọ́run gbọ̀ pé, yóò rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fún mi Ṣùgbọ́n a ó gbá wa jù sí erékùṣù kan Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru ọjọ́ kẹrìnlá, bí a ti ń gbé wa kọjá lọ láàrin òkun Ádíríà, láàrin ọ̀gànjọ́ àwọn atukọ̀ fura pé, àwọn súnmọ́ etí ilẹ̀ kan Nígbà tí wọ́n sì wọn òkun, wọ́n rí i ó jìn ní ogún ìgbọ̀nwọ́, nígbà tì í wọ́n sún ṣíwájú díẹ̀, wọ́n sì tún wọn òkun, wọn rí i pé ó jìn ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dógùn Nígbà tí wọ́n bẹ̀rù kí wọn má ṣe rọ́ lu orí òkúta, wọ́n sọ ìdákọ̀ro mẹ́rin sílẹ̀ ni ìdí-ọkọ̀, wọ́n ń rétí òjúmọ́ Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ ìgbàjá kalẹ̀ sí ojú òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀ Pọ́ọ̀lù wí fún balógun ọ̀rún àti fún àwọn ọmọ-ogun pé, Bí kò ṣe pé àwọn wọ̀nyí bá dúró nínú ọkọ̀ ẹ̀yin kí yóò lè là! Nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun gé okùn ìgbàjá, wọ́n jù ú sílẹ̀ kí ó ṣúbu sọ́hun Nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀, Pọ́ọ̀lù bẹ gbogbo wọn kí wọn jẹun díẹ̀, ó wí pé, Òní ni ó di ìjẹrìnlá tí ẹ̀yin ti ń rétí, ti ẹ kò dẹkun gbígbaàwẹ̀, tí ẹ kò sì jẹun Nítorí náà mo bẹ̀ yín, kí ẹ jẹun díẹ̀, nítorí èyí ni fún ìgbàlà yín nítorí irun kan kí yóò rẹ́ kúrò lórí ẹnìkan yín Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì mú àkàrà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn nígbà tí ó si bù ú, ó bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ Nígbà náà ni gbogbo wọn sì daráyá, àwọn pẹ̀lú sì gba oúnjẹ, Gbogbo wa tí ń bẹ nínú ọkọ̀-okun náà sì jẹ́ ọ̀rìnlúgba ènìyàn ó dín mẹ́rin Nígbà tí wọn jẹun yó tan, wọn bẹ̀rẹ̀ sí mu ọkọ̀-okun náà fúyẹ́, nípa kíkó àlìkámà dà sí omi Nígbà tí ilẹ̀ sí mọ́, wọn kò mọ́ ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn rí apá odò kan tí ó ní èbúté, níbẹ́ ni wọ́n gbérò, bóyá ó le ṣe é ṣe láti mu ọkọ̀ gúnlẹ̀ Nígbà tí wọ́n sì gé ìdákọ̀ró kúrò, wọn jù wọn sínú òkun, lẹ́sẹ̀kan náà wọn tú ìdè-ọkọ̀, wọn sì ta ìgbòkùn iwájú ọkọ̀ sí afẹ́fẹ́, wọn sì wakọ̀ kọjú sí etí-òkun Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí òkun méjì pàde, wọn fi orí-ọkọ̀ sọlẹ̀ iwájú rẹ̀ sì kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin, ó dúró, kò lè yí, ṣùgbọ́n agbára rírú omi bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ìdí ọkọ̀ náà Èrò àwọn ọmọ-ogun ni ki a pá àwọn òǹdè, kí ẹnikẹ́ni wọn má ba à wẹ̀ jáde sá lọ Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún ń fẹ́ gba Pọ́ọ̀lù là, ó kọ èrò wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn tí ó lè wẹ̀ kí wọn bọ́ sí òkun lọ sì ilẹ̀ Àti àwọn ìyókú, òmìíràn lórí pátakó, àti omíràn lórí àwọn igi tí ó ya kúrò lára ọkọ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe tí gbogbo wọn yọ, ní àlàáfíà dé ilẹ́ Ere-Kúsù Ni Mẹ́lítà Nígbà tí gbogbo wa sì yọ tan ni àwa tó mọ̀ pé, Mélítà ni a ń pè eré-kùṣù náà Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn alàìgbédè náà ṣe fún wa nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì sa ìdí ìwọ̀nwọ̀n-igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́ Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, Dájúdájú àpànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láàyè Òun sì gbọn ẹranko náà sínu iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣúbu lulẹ̀ kú lójijì nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí Ní agbégbé ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pọ́bílíù ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta Ó sì ṣe, baba Pọ́bílíù dubulẹ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn ẹni tí Pọ́ọ̀lù wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá Nígbà tí èyí sì ṣe tán, àwọn ìyókù tí ó ni àrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá Wọ́n sì bu ọlá púpọ́ fún wa nígbà tí a ń lọ, wọ́n sì fún wa ní ohun púpọ̀ tí a nílò ní ọ̀nà àjò wa Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, a wọ ọkọ̀ ojú-omi kan èyí tí ó lo àkókò otútù ní erékùsù náà Ó jẹ́ ọkọ̀ ojú-omi ti Alekisáńdírà, èyí tí ó àmì èyí tí se òrìsà ìbejì ti Kásítórù òun Pólúkísù Nígbà tí a sì gúnlẹ̀ ní Sírákúsì, a gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta Láti ibẹ̀ nígbà tí a lọ yíká a dé Régíónì nígbà tí ó sì di ọjọ́ kejì, afẹ́fẹ́ gúsù bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́, ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Pútéólì A sì rí àwọn arákùnrin kan níbẹ̀, tí wọ́n sì bẹ́ wá láti bá wọn gbé fún ọjọ́ méje bẹ́ẹ̀ ni a sì lọ sí ìhà Róòmù Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúró pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjọ títí wọ́n fi dé Api-fórù àti sí ilé-èrò mẹ́ta láti pàdé wa nígba tí Pọ́ọ̀lù sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le Nígbà tí a sì dé Róòmù, olórí àwọn ọmọ ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀sọ́ lọ́wọ́ ṣùgbọ́n wọ́n gba Pọ́ọ̀lù láàyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń sọ́ ọ Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, Pọ́ọ̀lù pe àwọn olórí Júù jọ nígbà tí wọ́n sì péjọ, ó wí fún wọn pé, Ẹ̀yin ara, bí ó ti se pé èmi kò se ohun kan lòdì sí àwọn ènìyàn, tàbí sí àṣà àwọn baba wa, ṣíbẹ̀ wọ́n fi mí lé àwọn ara Róòmù lọ́wọ́ ní òǹdè láti Jerúsálémù wá Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀ràn mi, wọ́n fẹ́ jọ̀wọ́ mi lọ́wọ́ lọ, nítorí tí wọn kò rí ẹ̀sùn kan tí ó tọ́ sí ikú pẹ̀lú mi Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù sọ̀rọ̀ lòdì sí i, èyí sún mí láti fi ọ̀ràn náà lọ Késárì, kì í ṣe pé mo ní ẹ̀sùn kan láti fi kan àwọn ènìyàn mi Ǹjẹ́ nítorí ọ̀ràn yìí ni mo ṣe ránṣẹ́ pè yín, láti rí yín àti láti bá yín sọ̀rọ̀ nítorí pé, nítorí ìrètí Ísírẹ́lì ni a ṣe fi ẹ̀wọ̀n yìí dè mí Wọ́n sì wí fún un pé, Àwa kò rí ìwé gbà láti Jùdíà nítorí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan nínú àwọn arákùnrin tí ó ti ibẹ̀ wá kò ròyìn, tàbí kí ó sọ̀rọ̀ ibi kan sí ọ Ṣùgbọ́n àwa ń fẹ́ gbọ́ lẹ́nu rẹ ohun tí ìwọ rò nítorí bí ó ṣe ti ìsìn ìyapa yìí ní, àwa mọ̀ pé, níbi gbogbo ni a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i Àwọn fi ẹnu kò lórí ọjọ́ tí wọn yóò se ìpàdé pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó tọ̀ ọ́ wa ni ilé àgbàwọ̀ rẹ̀ àwọn ẹni tí òun sọ àsọyé ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún, ó ń yí wọn padà nípa ti Jésù láti inú òfin Mósè àti àwọn wòlíì, láti òwúrọ̀ títí ó fi di àṣálẹ́ Àwọn ẹlòmíràn gba ohun tí ó wí gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn kò sì gbà á gbọ́ Nígbà tí ohùn wọn kò ṣọ̀kan láàrin ara wọn, wọ́n túká, lẹ́yìn ìgbà tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ kan pé, Ẹ̀mí Mímọ́ sọ òtítọ́ fún àwọn baba yín nígbà tí ó sọ láti ẹnu wòlíì Àìṣáyà wí pé Tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, kí ó sì wí pé, Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín à ti ni rírí ẹ̀yin yóò rí, ẹ kì yóò sí òye lati mọ̀ Nítorí ti àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì, etí wọn sì wúwo láti fi gbọ́, ojú wọn ni wọn sì ti di Nítorí kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn má ba à fi etí wọn gbọ́, àti kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn má ba à yípadà, àti kí èmi má ba à mú wọn láradá Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin mọ́ èyí pé, a rán ìgbàlà Ọlọ́run sí àwọn Kèfèrì wọ́n ó sì gbọ́ Nígbà tí ó ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn tan, àwọn Júù lọ, wọ́n bá ara wọn jíyàn púpọ̀ Pọ́ọ̀lù sì gbé ilé àgbàwọ̀ rẹ̀ lọ́dún méjì gbáko, ó sì ń gbà gbogbo àwọn tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá Ó ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, ó ń fi ìgboyà kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Jésù Kírísítì Olúwa, ẹnìkan kò dá a lẹ́kun Pétérù Mú Oníbárà Arọ Láradà Ní ọjọ́ kan Pétérù àti Jòhánù jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì ní wákàtí àdúrà tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ lẹ́nu-ọ̀nà tẹ́ḿpìlì ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ, Nígbà tí ó rí Pétérù àti Jòhánù bí wọn tí fẹ́ wọ inú tẹ́ḿpìlì, ó sagbe Pétérù sì tẹjúmọ́ ọn, pẹ̀lú Jòhánù, ó ní Wò wá! Ó sì fiyèsí wọn, ó ń réti láti rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn Pétérù wí pé, Góòlù àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fifún ọ Ní orúkọ Jésù Kírísítì ti Násárẹ́tì, dìde kí o sì máa rìn Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde lójúkán náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run Gbogbo ènìyàn sì rí i, ó ń rìn, ó sì yin Ọlọ́run Wọn sì mọ̀ pé òun ni ó ti jókòó tí ń ṣagbe lẹ́nu ọ̀nà Dáradára ti tẹ́ḿpìlì náà hà, sì ṣe wọn, ẹnu sì yà wọn gidigidi sí ohun tí ó ṣe lára rẹ̀ Bí arọ ti a mú láradá sì ti di Pétérù àti Jòhánù mú, gbogbo ènìyàn júmọ́ sure tọ̀ wọ́n lọ ni ìloro ti a ń pè ní ti Sólómónì, pẹ̀lú ìyàlẹ́nú ńlá Nígbà tí Pétérù sì rí i, ó dáhùn, ó wí fún àwọn ènìyàn pé, Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, è é ṣe tí háà fi ń ṣe yín sí èyí Tàbí è é ṣe ti ẹ̀yin fi tẹjúmọ́ wa, bí ẹni pé agbára tàbí ìwà mímọ́ wa ni àwa fi ṣe é ti ọkùnrin yìí fi ń rìn Ọlọ́run Ábúráhámù, àti ti Ísáàkì, àti ti Jákọ́bù, Ọlọ́run àwọn baba wa, òun ni ó ti yin Jésù ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo ẹni tí ẹ̀yin ti fi lé wọn lọ́wọ́, tí ẹ̀yin sì sẹ́ níwájú Pílátù, nígbà tí ó ti pinnu rẹ̀ láti dá a sílẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin sẹ́ Ẹni-Mímọ́ àti Olóòtọ̀ náà, ẹ̀yin sì béèrè kí a fi apànìyàn fún un yín Ẹ̀yin sì pa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìyè, ẹni tí Ọlọ́run sì ti jí dìde kúrò nínú òkú ẹlẹ́rìí èyí ti àwa jẹ́ Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀ Orúkọ Jésù àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ará, mo mọ̀ pé nípa àìmọ̀ ni ẹ̀yin fi ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí yín pẹ̀lú ti ṣe Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti se ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kírísítì rẹ̀ yóò jìyà Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, àti kí ó baà lè rán Kírísítì tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀ àní Jésù Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti sẹ̀ Mósè wí pé, Olúwa Ọlọ́run yín yóò gbé wòlíì kan dìde fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi òun ni ẹ̀yin yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo tí yóò máa sọ fún un yín Yóò sì se, olúkúlùkù ọkàn ti kò bá gbọ́ ti wòlíì náà, òun ni a ó parun pátapáta kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ Àní, gbogbo àwọn wòlíì láti Sámúẹ́lì wá, àti àwọn tí ó tẹ̀lé e, iye àwọn tí ó ti sọ̀rọ̀, wọn sọ ti ọjọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì, àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti bá àwọn baba yín dá nígbà tí ó wí fún Ábúráhámù pé, Láti ipasẹ̀ irú àwọn ọmọ rẹ̀ ni a ó ti bùkún fún gbogbo ìdílé ayé Nígbà ti Ọlọ́run jí Jésù Ọmọ rẹ̀ dìde, ó kọ́ rán an sí i yín láti bùkún fún un yín, nípa yíyí olúkúlùkù yín padà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀ Pétérù Ati Jòhánù Níwájú Àwọn Sádúsì Bí wọn sì tí ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, àwọn àlùfáà àti olórí ẹ̀sọ́ tẹ́ḿpílì àti àwọn Sádúsì dìde sí wọn Inú bí wọn, nítorí tí wọn kọ́ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń wàsúù àjíǹde kúrò nínú òkú nínú Jésù Wọn sì náwọ́ mú wọn, wọn sì tì wọ́n mọ́ ilé túbú títí ó fi dí ijọ́ kejì nítorí tí alẹ́ ti lẹ́ tan Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́ iye àwọn ọkùnrin náà sì tó ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n Ó sì ṣe níjọ kejì, àwọn olórí wọn àti àwọn alàgbà àti àwọn olùkọ́ni ní òfin péjọ sí Jerúsálémù Àti Ánà olórí àlùfáà, àti Káíáfà, àti Jòhánù, àti Alekisáńdérù, àti iye àwọn tí i ṣe ìbátan olórí àlùfáà Wọ́n mú Pétérù àti Jòhánù dúró níwájú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn pé, Nípa agbára tàbí orúkọ wo ni ẹ̀yin fi ṣe èyí Nígbà náà ni Pétérù kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ̀yin olórí àti ẹ̀yin alàgbà àwọn ènìyàn! Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónì ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá, Kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì pé, ni orúkọ Jésù Kírísítì ti Násárétì, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá Èyí ni  òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, tí ó sì di pàtàkì igun ilé Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlomìíràn nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run ti a fifún ni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là Nígbà tí wọ́n sì kíyèsí ìgboyà Pétérù àti Jòhánù, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jésù gbé Nígbà tí wọ́n sì ń wo ọkùnrin náà tí a mú láradá, tí ó bá wọn dúró, wọn kò rí nǹkan wí sí i Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sì ti pàṣẹ pé kí wọn jáde kúrò ní ìgbìmọ̀, wọ́n bá ara wọn gbérò Wí pé, Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí Ní ti pé iṣẹ́ àmì tí ó dájú tí ọwọ́ wọn ṣe, ó hàn gbangba fún gbogbo àwọn tí ń gbé Jerúsálémù àwa kò sì lè ṣe èyí Ṣùgbọ́n kí ó má ba à tàn kálẹ̀ ṣíwájú mọ́ láàrin àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a kìlọ̀ fún wọn pé, láti ìsinsin yìí lọ kí wọn má ṣe fi orúkọ yìí sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni mọ́ Wọ́n sì pè wọ́n, wọ́n pàsẹ fún wọn, kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ tàbí kọ́ni rárá mọ́ ní orúkọ Jésù Ṣùgbọ́n Pétérù àti Jòhánù dáhùn, wọ́n sì wí fún wọn pé, Bí ó bá tọ́ lójú Ọlọ́run láti gbọ́ tiyín ju ti Ọlọ́run lọ ẹ gbà á rò Àwa kò lè sàìmá sọ ohun tí àwa ń rí, tí a sì ti gbọ́ Nígbà tí wọ́n sì kìlọ̀ fún wọn sí i, wọn fi wọ́n sílẹ̀ lọ, nígbà tí wọn kò ì tí ì rí nǹkan tí wọn ì bá fi jẹ wọ́n ní ìyà, nítorí àwọn ènìyàn nítorí gbogbo wọn ni wọ́n yin Ọlọ́run lógo fún ohun tí ó ṣe Nítorí ọkùnrin náà lára ẹni tí a ṣe iṣẹ́ àmì ìmúlaradà, ju ẹni-ogoji ọdún lọ Nígbà tí wọ́n sì ti fi wọ́n sílẹ̀ wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà sọ fún wọn Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, Olúwa, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, àti òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn Ìwọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ti ẹnu Dáfídì baba wa ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé  E é ṣe tí àwọn kéférì fi ń bínú, àti tí àwọn ènìyàn ń gbérò ohun asán Àwọn ọba ayé dìde, àti àwọn ìjòyè kó ara wọn jọ sí Olúwa, àti sí Ẹni-Àmìn òróró rẹ̀ Àní nítòótọ́ ní Hẹ́rọ́dù, àti Pọ́ńtíù Pílátù, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jésù Ìrànṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi òróró yàn, Láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣẹ Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Olúwa, kíyèsí ìhàlẹ̀ wọn kí ó sì fi fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà ńlá sọ ọ̀rọ̀ rẹ Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradà, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jésù Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tan, ibi tí wọ́n gbé péjọ pọ̀ sí mì tìtì gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ìjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan kò sì sí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀ ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìsọ̀kan Agbára ńlá ni àwọn àpósítélì sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jésù Olúwa, Oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn Nítorí kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ṣe aláìní, nítorí iye àwọn tí ó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n, wọ́n sì mú owó ohun tí wọn tà wá Wọ́n sì fi í lélẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ àwọn àpósítélì, wọn sì ń pín fún olukúlúkù gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe aláìní sí Àti Jóṣéfù, tí a ti ọwọ́ àwọn àpósítélì sọ àpèlé rẹ̀ ní Bánábà , ẹ̀yà Léfì, àti ará Sáípúrọ́sì Ó ní ilẹ̀ kan, ó tà á, ó mú owó rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn àpósítélì Ananíyà Àti Sàfírà Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Ananíyà, pẹ̀lú Sàfírà aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan, Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apákan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apákan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn àpósítélì Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé, Ananíyà, È é ṣe ti sátánì fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí-Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apákan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ È é há ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣékè sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run Nígbà tí Ananíyà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó subú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́ Àwọn ọdọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé Pétérù sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Ananíyà gbà lórí ilẹ̀ Ó sì wí pé, Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ nìyẹn Pétérù sí wí fún un pé, È é ṣe ti ẹ̀yin fohùn sọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Mímọ́ wò Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ lẹ́nu ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bá ọkọ rẹ̀ Ẹ̀rù ńlá sì bá gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí A sì ti ọwọ́ àwọn àpósítélì ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrin àwọn ènìyàn Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Sólómónì Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí bẹ́ẹ̀dì àti ẹní kí òjìji Pétérù ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerúsálémù ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́ a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlúfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sádúsì wọ̀ Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn àpósítélì wọn sì fi wọ́n sínú túbú Ṣùgbọ́n ní òru, áńgẹ́lì Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú ó sì mú wọn jáde Ó sì wí pé Ẹ lọ dúró nínú tẹ́ḿpìlì kí ẹ sì máa sọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́ré fún àwọn ènìyàn Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹ́ḿpílì lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpèjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn àpósítélì wá Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olùsọ́ dé ibẹ̀ wọn kò sì rí wọn nínú túbú, wọn pàda wá, wọn sí sọ fún wọn pé, Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùsọ́ dúró lóde níwájú ilẹ́kùn ṣùgbọ́n nígbà tí àwa sí ilẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú Nígbà tí olórí ẹ̀sọ́ tẹ́ḿpílì àti àwọn olórí àlùfáà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n dààmú nítorí wọn kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ yìí yóò yọrí sí Nígbà náà ni ẹnìkan dé, ó wí fún wọn pé, Wò ó, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀yin fi sínú túbú wà ní tẹ́ḿpílì, wọn dúró wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olúsọ́, ó sì mú àwọn àpósítélì wá Wọn kò fi ipá múwọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta Nígbà tí wọn sì mú àwọn àpósítélì dé, wọn mú wọn dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀ olórí àlúfáà sì bi wọ́n léèrè Ó wí pé, Àwa kò ha ti kìlọ̀ fún un yín gidigidi pé, kí ẹ má ṣe fi orúkọ yìí kọ́ni Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ti fi ìkọ́ni yín kún Jerúsálémù, ẹ sì ń pete àti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sí orí wá Ṣùgbọ́n Pétérù àti àwọn àpósítélì dáhùn, wọ́n sì wí pé, Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ! Ọlọ́run àwọn baba wa jí Jésù dìde kúrò ní ipò òkú, ẹni tí ẹ̀yin pa nípa gbígbé kọ́ sí orí igi Òun ni Ọlọ́run fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-aladé àti Olùgbàlà láti fi ìrònúpìwàdà àti ìdàríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Ísírẹ́lì Àwa sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti se ẹlẹ́rìí pẹ̀lú, tí Ọlọ́run fifún àwọn tí ó gbà á gbọ́ Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọ́n gbérò láti pa wọ́n Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àjọ ìgbìmọ̀, tí a ń pè ni Gàmálíẹ́lì, Farisí àti àmofìn, tí ó ní ìyìn gidigidi lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó dìde dúró, ó ni kí a mú àwọn àpósítélì bì sẹ́yìn díẹ̀ Ó sì wí fún wọn pé Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ kíyèsí ara yín lóhun tí ẹ̀yin ń pète láti ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí Nítorí ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí ni Téúdà dìde, ó ń wí pé, ẹni ńlá kan ní òun ẹni tí ìwọ̀n irínwó ọkùnrin dara wọn pọ̀ mọ́ ṣùgbọ́n a pá a àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ sì túká, tí wọn sí di asán Lẹ́yìn ọkùnrin yìí ni Júdà ti Gálílì dìde ni àkókò kíka àwọn ènìyàn, ó sì fa ẹni púpọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ òun pẹ̀lú ṣègbé àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ ni a fọ́nká Ǹjẹ́ èmi wí fún un yín nísinsin yìí, Ẹ gáfárà fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí ẹ sí fi wọn sílẹ̀, nítorí bí ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, a ó bì í ṣúbu Ṣùgbọ́n bí ti Ọlọ́run bá ní, ẹ̀yin kì yóò lè bì í ṣúbu kí ó má ba à jẹ́ pé, a rí yín bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà Wọ́n sì gbà ìmọ̀ràn rẹ̀ Wọn pe àwọn àpósítélì wọlé, wọ́n lù wọ́n Wọn sí kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ ni orúkọ Jésù mọ́, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ lọ Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀ wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀ Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ḿpílì àti ni ojúlé dé ojúlé, wọn kò dẹ́kùn kíkọ́ni àti láti wàásù ìyìn rere náà pé Jésù ni Kírísítì Yíyan Àwọn Méje Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùn-sínú wà ní àárin àwọn Gíríkì tí se Júù àti àwọn Hébérù tí se Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín-fúnni ojoojúmọ́ Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábílì Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí-Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ wọ́n sì yan Sítéfánù, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí-Mímọ́ àti Fílípì, àti Pírókórù, àti Níkánórù, àti Tímónì, àti Páríménà, àti Níkólásì aláwọ̀se Júù ara Ańtíókù Ẹni tí wọ́n mú dúró níwájú àwọn Àpósítélì nígbà tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbilẹ̀, iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i gidigidi ni Jerúsálémù, ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sí fetí sí tí ìgbàgbọ́ náà Sítéfánù tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ àmì ńlá láàrin àwọn ènìyàn Ṣùgbọ́n àwọn kan dìde nínú àwọn ti ń se ara sínágógù, tí a ń pè ní Líbátaínì Àwọn Júù Kírénè àti ti Alekisáńdíríà àti ti Kílíkíà, àti ti Ásíà wá, wọ́n ń bá Sítéfánù jiyàn, ṣùgbọ́n wọn kò sí lè ko ọgbọ́n àti Ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀ lójú Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọkùnrin kan ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kí wọn ń wí pé, Àwa gbọ́ tí Sítéfánù ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Mósè àti sí Ọlọ́run Wọ́n sí ru àwọn ènìyàn sókè, àti àwọn alàgbà, àti àwọn olùkọ́ni ní òfin Wọ́n dìde sí i, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sí iwájú àjọ ìgbìmọ̀ Wọ́n sí mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, ti wọn wí pé, Ọkùnrin yìí kò sinmi láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ibi mímọ́ yìí, àti sí òfin Nítorí àwa gbọ́ o wí pé Jésù ti Násárẹ́tì yìí yóò fọ́ ibí yìí, yóò sì yí àṣà ti Mósè fifún wa padà Gbogbo àwọn tí ó sì jókò ni àjọ ìgbìmọ̀ tẹjúmọ́ Sítéfánù, wọ́n sì rí ojú rẹ̀ dàbí ojú ańgẹ́lì Ọ̀rọ̀ Sítéfánù Sí Àwọn Àjọ Ìgbìmọ̀ Nígbà náà ni olorí àlùfáà wí pé, Òtítọ́ ha ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́ fi kàn ọ́ bí Ní ìdáhùn sí èyí ó wí pé, Ẹ̀yin arakùnrin àti ẹ̀yin baba, ẹ fetísílẹ̀ sí mi! Ọlọ́run ògo fi ara hàn fún Ábúráhámù baba wa, nígbà tí ó wà ni Mesopotamíà, kí ó to ṣe àtìpó ni Háránì Ọlọ́run fún un pé, Jáde kúrò ni orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí ó sì lọ sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́ Nígbà náà ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, ó sì ṣe àtipó ni Háránì Lẹ́yìn ìgbà tí baba rẹ̀ sì kú, Ọlọ́run mú un sípò padà wá sí ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀yin ń gbé báyìí Kò sí fún un ni ìní kan, àní tó bi ìwọ̀n ààyè ẹṣẹ̀ kan Ṣùgbọ́n Ọlọ́run se ìlérí fún pé, òun yóò fi ilẹ̀-ìní náà fún un àti fún àwọn irú ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí kò tí ì ní ọmọ Ọlọ́run sì sọ báyìí pé Irú-ọmọ rẹ̀ yóò ṣe àtìpó ni ilẹ̀ àjèjì wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú ni irínwó ọdún Ọlọ́run wí pé, Orílẹ̀-èdè náà tí wọn ó ṣe ẹrú fún ni èmi ó dá lẹ́jọ́ lẹ́yìn náà ni wọn ó sì wá sìn mí níhín yìí Ó sì fún Ábúráhámù ni májẹ̀mú ìkọlà Ábúráhámù bí Ísáákì, ó kọ ọ́ ní ilà-abẹ́ ni ijọ́ kẹjọ tí ó bí i Ísáákì sí bí Jákọ́bù, Jákọ́bù sì bí àwọn baba ńlá méjìlá Àwọn baba ńlá sí ṣe ìlara Jósẹ́fù, wọ́n sì tà á sí Íjíbítì ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì yọ ọ́ kúrò nínú ìpọ́njú rẹ̀ gbogbo Ó sì fún Jósẹ́fù ní ọgbọ́n, ó sì mú kí ó rí ojúrere Fáráò ọba Íjíbítì òun sì fi jẹ baálẹ̀ Íjíbítì àti gbogbo ilé rẹ̀ Ìyàn kan sì mú ni gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì àti ni Kénánì, àti ìpọ́njú ńlá, àwọn baba wa kò sì rí oúnjẹ Ṣùgbọ́n nígbà tí Jákọ́bù gbọ́ pé Àlìkámà ń bẹ ni Íjíbítì, ó rán àwọn baba wa lọ lẹ́ẹ̀kínní Nígbà kejì Jósẹ́fù fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀, a sì tún fi wọ́n hàn fún Fáráò Lẹ́yìn èyí, Jósẹ́fù ránsẹ́ pe Jákọ́bù baba rẹ̀, àti àwọn ìbátan rẹ̀ wá sọ̀dọ̀ rẹ, gbogbo wọ́n sì tó àrúndínlọ́gọ́rin ènìyàn Nígbà náà ni Jákọ́bù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì, ní ibi tí òun àti àwọn baba wa kú sí A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣékémù, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Ábúráhámù rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Ámórì ní Sékémù ní iye-owó wúrà kan Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí ó ṣe fún Ábúráhámù sẹ kù dẹ̀dẹ̀, àwọn ènìyàn wa ń gbérù si gidigidi ní iye ní ilẹ̀ Íjíbítì Ṣùgbọ́n ọba mị̀íràn, ẹni tí kò mọ ohunkóhun nípa Jósẹ́fù, di alásẹ lórí ilẹ̀ Íjíbítì Òun náà ni ó ṣe àrékekè sí àwọn ìbátan wa Wọn sì hùwà búburú sí àwọn baba wa, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi já àwọn ọmọ-ọwọ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn nítorí kí wọn má ṣe yè Ní àkókò náà ni a bí Mósè, ẹni tí ó lẹ́wà púpọ̀, tí wọn sí bọ́ lóṣù mẹ́ta ni ilé baba rẹ̀ Nígbà tí wọn sí gbe é sọnù, ọmọbìnrin Fáráò gbé e, ó sì tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ara rẹ̀ A sì kọ́ Mósè ni gbogbo ọgbọ́n ara Íjíbítì, ó sì pọ̀ ni ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe Nígbà tí Mósè di ọmọ ogójì ọdún, ó sọ sí i lọ́kàn láti lọ bẹ àwọn ọmọ Isríẹ́lì ará rẹ̀ wò Nígbà tí ó sì rí ọ̀kan nínú wọ́n tí ara Éjíbítì kan ń jẹ́ ní ìyà, ó gbéjà rẹ̀, ó gbẹ̀sàn ẹni tí wọ́n jẹ ní ìyà nípa lílu ara Íjíbítì náà pa Mósè rò bí àwọn ará òun mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ti ọwọ́ òun gbà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ Ní ọjọ́ kejì Mósè yọ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì bí wọ́n ti ń jà Òun ì bá sí parí rẹ̀ fún wọn Ó wí pé, Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin è é ṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fínràn sí ẹnìkejì rẹ̀ tì Mósè sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó wí pé, Ta ni ó fi ọ jẹ olórí àti onídàjọ́ wa Àbí ìwọ ń fẹ́ pa mi gẹ́gẹ́ bí o ti pa ará Íjíbítì lánàá Mósè sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Mídíànì, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Mósè ní ijù, ní òkè Sínáì, nínú ọ̀wọ́ iná ìgbẹ́ Nígbà tí Mósè sì rí i, ẹnu yà á sí ìran náà nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti wò ó fín, ohùn Olúwa kọ sí i, Wí pé Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísáákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù, Mósè sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dàṣà láti wò ó mọ́ Olúwa sì wí fún un pé, Tú bátà rẹ kúrò ni ẹsẹ̀ rẹ, nitorí ibi tí ìwọ gbé dúró sí yìí ilẹ̀ mímọ́ ni Ní rírí mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n Wá nísinsìn yìí, èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì Mósè náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ ańgẹ́lì, tí ó farahàn án ní ìgbẹ́, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì ní ilẹ̀ Íjíbítì, àti ni òkun pupa, àti ni ihà ní ogójì ọdún Èyí ni Mósè náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú ańgẹ́lì náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sínáì, àti pẹ̀lú àwọn baba wa ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀ Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì Wọ́n wí fún Árónì pé Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ ọ̀nà ṣáájú wa nítorí bí ó ṣe ti Mósè yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Íjíbítì, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí Wọ́n sì rúbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn se Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé  Ẹ̀yin hà mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi ní ogójì ọdún ní ijù bí, Ìwọ ilé Ísírẹ́lì Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gba ojúbọ Mólókù, àti ìràwọ̀ Ráfánì òrìṣà yín, àwọn òrìṣà tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Bábílónì Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijú Èyí tí a se gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mósè sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ tí ó ti rí Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Jóṣúà wá sí ilẹ̀-ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókó Dáfídì Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jákọ́bù Ṣùgbọ́n Sólómónì ni ó kọ́ ilé fún un, Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé  Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni àpòtí ìtìsẹ̀ mi Irú ilé kínní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi ni Olúwa wí Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi isinmi mi Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí Ẹ̀yin ọlọ́rùn-líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yín rí Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́! Ǹjẹ́ ó tilẹ̀ wà nínú àwọn wòlíì tí àwọn baba yín kò ṣe inúnibíni sí Wọn sì ti pa àwọn ti ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwá Ẹni Olódodo náà Nísinsin yìí ẹ̀yin ti dalẹ̀ rẹ̀ ẹ̀yin sí ti pa Ẹ̀yin tí ó gba òfin, gẹ́gẹ́ bí àwọn ańgẹ́lì ti fi fún ni, tí ẹ kò sí pa á mọ́ Nígbà tí wọn sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọn sì payín keke sí i Ṣùgbọ́n Sítéfánù, ẹni tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó tẹjúmọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọ́run, àti Jésù dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run Ó sì wí pé, Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ Ènìyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run Nígbà náà ni wọn kígbe ní ohùn rara, wọn sí di etí wọ́n, gbogbo wọn sì sáré sí i, wọ́n sì rọ́ lù ú, wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ́ ní òkúta àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Sọ́ọ̀lù Bí wọ́n ti ń sọ ọ́ ní òkúta, Sítéfánù gbàdúrà wí pé, Jésù Olúwa, gba ẹ̀mi mi Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ Wọ́n Ṣe Inúnibínu Sí Ìjọ, Wọ́n Sì Túkà Sọ́ọ̀lù sì wà níbẹ̀, ó sì ní ohùn sí ikú rẹ̀ Ní àkókò náà, inúnibini ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerúsálémù, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Jùdíà àti Samaríà, àyàfi àwọn àpósítélì Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Sítéfánù lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀ Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù bẹ̀rè sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo, wọn ń wàásù ọ̀rọ̀ náà Fílípì sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaríà, ó ń wàásù Kírísítì fún wọn Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ̀, tí wọn sì rí iṣẹ́ àmì tí Fílípì ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkan kan fíyèsí ohun tí ó ń sọ Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúkùn-ún ni ó sì gba ìmúláradá Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà, tí a ń pè ní Símónì, tí ó ti máa ń pa idán ní ìlú náà, ó sì mú kí ẹnu ya àwọn ará Samaríà Ó sì máa ń fọ́nnu pé ènìyàn ńlá kan ni òun Ẹni tí gbogbo èwe àti àgbà fiyèsí tí wọ́n sì ń bọlá fún wí pé, Ọkùnrin yìí ní agbára Ọlọ́run ti ń jẹ́ Ńlá Wọ́n bọlá fún un, nítorí ọjọ́ pípẹ́ ni ó ti ń pa idán fún ìyàlẹ́nu wọn Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gba Fílípì gbọ́ bí ó ti ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba Ọlọ́run, àti orúkọ Jésù Kírísítì, a bámítíìsì wọn Símónì tikararẹ̀ sì gbàgbọ́ pẹ̀lú nígbà ti a sì bámitíìsì rẹ̀, ó sì tẹ̀ṣíwájú pẹ̀lú Fílípì, ó wo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ agbára tí ń ti ọwọ́ Fílípì ṣe, ẹnu sì yà á Nígbà tí àwọn àpósítélì tí ó wà ní Jerúsálémù sí gbọ́ pé àwọn ara Samaríà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Pétérù Àti Jòhánù sí wọn Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́ nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bá lé ẹnikẹ́ni nínú wọn kìkì pè a bamitíìsì wọn lórúkọ Jésù Olúwa ni Nígbà náà ni Pétérù àti Jòhánù gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́ Nígbà tí Símónì rí i pé nípa gbígbe ọwọ́ leni ni a ń ti ọwọ́ àwọn àpósítélì fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n, ó wí pé, Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn wí pé, Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run! Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déedé níwájú Ọlọ́run Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búrurú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dári ète ọkàn rẹ jì ọ́ Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹrò ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀ Nígbà náà ni Símónì dáhùn, ó sì wí pé, Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, ti wọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Pétérù àti Jòhánù padà lọ sí Jerúsálémù, wọ́n sì wàásù ìyìn rere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn Samaríà Ańgẹ́lì Olúwa sì sọ fún Fílípì pé, Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerúsálémù lọ sí Gásà Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ sí kíyèsí, ọkùnrin kan ará Etiópíà, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọdọ̀ Káńdákè ọba-bìnrin àwọn ara Etiópíà, ẹni tí í se olórí ìsúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerúsálémù láti jọ́sìn, Òun sì ń padà lọ, ó sì jókòó nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó ń ka ìwé wòlíì Àìṣáyà Ẹ̀mí sì wí fún Fílípì pé, Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí Fílípì si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Àìṣáyà, Fílípì sì bí i pé, Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí Ó sì dáhùn wí pé, Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà Ó sì bẹ Fílípì kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó Ibi-ìwé-mímọ́ tí Ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olúrẹ́run rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́-ododo dùn ún Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀ Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Fílípì pé, Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmìíràn Fílípì sí ya ẹnu rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé-mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìyìn rere ti Jésù fún un Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan ìwẹ̀fà náà sì wí pé, Wò ó, omi nìyí Kín ni ó dá mi dúró láti bamitíìsì Fílípì sì wí pé, Bí ìwọ bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, a lè bamitíìsì rẹ Ìwẹ̀fà náà sì dáhùn pé, Mo gbàgbọ́ pé Jésù Kírísítì Ọmọ Ọlọ́run ni Ó sì pàṣẹ kí kẹ̀kẹ́ dúró jẹ́ àwọn méjèèjì Fílípì àti Ìwẹ̀fà sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi, Fílípì sì bamitíìsì rẹ̀ Nígbà tí wọ́n sí jáde kúrò nínú omi Ẹ̀mí Olúwa gbé Fílípì lọ, ìwẹ̀fà kò sì rí i mọ́ nítorí tí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀ Fílípì sì bá ara rẹ̀ ní ìlú Ásótù, bí ó ti ń kọ́ja lọ, o wàásù ìyìn rere ní gbogbo ìlú, títí ó fi dé Kesaríà Ìyípadà Sáùlú Ṣùgbọ́n síbẹ̀, Ṣọ́ọ̀lù sí ń tẹ̀síwájú nínú mímí-èémí ìhalẹ̀-mọ́ni àti ìpani sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Olúwa Ó tọ olórí alúfà lọ, ó bèèrè ìwé lọ́wọ́ rẹ̀ sí sínágọ́gù tí ń bẹ ní ìlú Dámásíkù pé, bí òun bá rí ẹnikẹ́ni tí ń bẹ ni Ọ̀nà yìí, ìbaà ṣe ọkùnrin, tàbí obìnrin, kí òun lè mú wọn ní dídè wá sí Jerúsálémù Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ, ó sì súmọ́ Dámásíkù lójijì, ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run wá mọlẹ̀ yí i ká Ó sì subú lulẹ̀, ó gbọ́ ohùn tí ó ń fọ̀ sí i pé, Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù, è é ṣe ti ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi Ó sì wí pé, Ìwọ ta ni, Olúwa Olúwa sì wí pé, Èmi ni Jésù, ẹni ti ìwọ ń ṣe inúnibíni sí Ó sì ń wárìrì, ẹnu sì yà á, ó ni Olúwa, kín ní ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe Olúwa sì wí fún pé, Dìde, kí o sì lọ sí ìlú náà, a ó sì sọ fún ọ nípa ohun tí ìwọ yóò ṣe Àwọn ọkùnrin tí wọ́n sì ń bá Sọ́ọ̀lù lọ àjò dúró, wọn kò sì le sọ ohun kan, wọn gbọ́ ohùn náà ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹnìkan Ṣọ́ọ̀lù sì dìde ní ilẹ̀ nígbà tí ojú rẹ̀ sì lá kò rí ohunkóhun ṣùgbọ́n wọ́n fà á lọ́wọ́ wọ́n sì mú un wá sí Dámásíkù Ó sì gbé ọjọ́ mẹ́ta ni àìríran kò sì jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu Ọmọ-ẹ̀yìn kan sì wà ní Dámásíkù, tí a ń pè ni Ananíyà! Olúwa sì wí fún un lójúran pé, Ananíyà! Ó sì wí pé, Wò ó, èmi nìyí, Olúwa Olúwa sì wí fún un pé, Dìde kí ó sì lọ sí ilé Júdà ní Òpópónà Tààrà, kí ó sì bèèrè ẹni tí a ń pè ni Ṣọ́ọ̀lù, ara Tásọ́sì, sá wò ó, ó ń gbàdúrà Òun sì tí ri ọkùnrin kan lójúran ti a ń pè ni Ananíyà o wọlé, ó sì fi ọwọ́ lé e, kí ó lè ríran Ananíyà sì dáhùn wí pé, Olúwa mo tí gbúrò ọkùnrin yìí lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, gbogbo búrukú ti ó ṣe sí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ni Jerúsálémù Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhínyìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, Má a lọ nítorí ohun-èlò ààyò ni òun jẹ́ fún mi, láti gbé orúkọ mi lọ sí iwájú àwọn aláìkọlà, àti àwọn ọba, àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Nítorí èmi o fi gbogbo ìyà ti kò le ṣàìjẹ nítorí orúkọ mi hàn án Ananíyà sì lọ, ó sì wọ ilé náà, nígbà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù, ó sì wí pé, Arákùnrin Sọ́ọ̀lù, Olúwa ni ó rán mi, Jésù tí ó fi ara hàn ọ lọ́nà tí ìwọ bá wá, kí ìwọ baà lè rìran, kí ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ Lójúkan náà nǹkan kan ti ó dàbí ìpẹ́ sì bọ kúrò lójú rẹ̀, ó sì ríran ó sì dìde, a sì bamitíìsì rẹ̀ Nígbà tí ó sì jẹun, ara rẹ̀ mókun Ṣọ́ọ̀lù sì wá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní Dámásíkù ní ọjọ́ púpọ̀ Lójúkan náà ó sì ń wàásù Kírísítì nínú àwọn sínágógù pé, Ọmọ Ọlọ́run ní í ṣe Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fòórò àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerúsálémù Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhìnyìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Dámásíkù, ó fi hàn pé, èyí ni Kírísítì náà Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mímọ̀ fún Ṣọ́ọ̀lù Wọ́n sì ń sọ́ ẹnu-bodè pẹ̀lú lọ́san àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n Nígbà ti Ṣọ́ọ̀lù sì de Jerúsálémù ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni Ṣùgbọ́n Bánábà mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn àpósítélì, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Dámásíkù ní orúkọ Jésù Ó sì pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerúsálémù Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Jésù Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Hélénì, ó sì ń jà wọ́n níyàn ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a Nígbà tí àwọn arákùnrin sì mọ̀, wọ́n mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kesaríà, wọ́n sì rán an lọ sí Tásísì Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Jùdíà àti ni Gálílì àti ni Samaríà, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i Ó sì ṣe, bí Pétérù ti ń kọjá lọ káàkiri láàrin wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú si ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ń gbé ni Lídà Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Áénéà tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní àrùn ẹ̀gbà Pétérù sì wí fún un pé, Áénéà, Jésù Kírísítì mú ọ láradá dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe Ó sì dìde lójúkan náà Gbogbo àwọn tí ń gbé Lídà àti Sárónì sì rí i, wọn sì yípadà sí Olúwa Ọmọ-ẹyìn kan sí wà ní Jópà ti a ń pè ni Tàbítà, èyí tí ó túmọ̀ sí Dọ́kásì obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ-àánú ṣíṣe Ní àkókò náà ni ó wà nínú àìsàn, ó sì kú, wọ́n sì wẹ òkú rẹ̀, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí iyàrá òké Bí Lídà sì ti súnmọ́ Jópà, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹyìn gbọ́ pé Pétérù wà níbẹ̀, wọ́n rán ọkùnrin méjì sí i láti bẹ̀ ẹ́ pé, Má ṣe jáfara láti dé lọ́dọ̀ wa Pétérù sí dìde, ó sì bá wọn lọ Nígbà tí ó dé, wọ́n mú un lọ sí ìyará òkè náà gbogbo àwọn opó sí dúró tì í wọn sọkún, wọ́n sì ń fi ẹ̀wù àti aṣọ tí Dọ́kásì dá hàn án, nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn Ṣùgbọ́n Pétérù ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà ó sì yípadà sí òkú, ó ní Tàbítà, dìde Ó sì la ojú rẹ̀ nígbà tí ó sì rí Pétérù, ó dìde jókòó Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi i lé wọn lọ́wọ́ láàyè Èyí sì di mímọ̀ já gbogbo Jópà ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́ Ó gbé ọjọ́ púpọ̀ ni Jópà ní ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan Símónì oníṣọ̀nà-awọ Ìdájọ́ àwọn aládùúgbò Ísírẹ́lì Àwọn ọ̀rọ̀ Ámósì, ọ̀kan lára àwọn olùsọ́ àgùntàn Tékóà ohun tí o rí nípa Ísírẹ́lì ní ọdun méjì ṣáàjú ilẹ̀ riri, nígbà tí Úsáyà ọba Júdà àti Jéróbóámù ọmọ Jéóhásì jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì Ó wí pé Olúwa yóò bú jáde láti Síóní ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jérúsálẹ́mù wá Ibùgbé àwọn olùṣọ́ àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀, Orí-òkè Kámẹ́lì yóò sì rọ Èyí ni ohun tí Olúwa wí Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Dámásíkù, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi pada Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gílíádì Pẹ̀lú ohun èlo irin tí ó ní eyín mímú Èmi yóò rán iná sí ilé Hásáélì Èyí ti yóò jó àwọn ààfin Bẹni-Hádádì run Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdáàbú Dámásíkù Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Áfénì run Àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Bẹti-Édénì Àwọn ará a Árámù yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kírì, ni Olúwa wí Èyí ni ohun tí Olúwa wí Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Gásà, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Gẹ́gẹ́ bí í oníṣòwò ẹrú, ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbékùn Ó sì tà wọ́n fún Édómù, Èmi yóò rán iná sí ara odi Gásà tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run Èmi yóò ké àwọn olùgbé Ásódì kúrò Àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Ákélónì mú Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ékírónì títí tí ìyókù Fílístínì yóò fi ṣègbé, ni Olúwa Ọlọ́run wí Èyí ni ohun tí Olúwa wí Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Tírè àní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbékùn fún Édómù Wọn kò sì nán-án-ní májẹ̀mú ọbàkan, Èmi yóò rán iná sí ara odi Tírè Tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run Èyí ni ohun tí Olúwa wí Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Édómù, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀, Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́ Èmi yóò rán iná sí orí Témánì Tí yóò jó gbogbo ààfin Bósírà run Èyí ni ohun tí Olúwa wí Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ámónì àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gílíádì kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn Èmi yóò rán iná sí ara odi Rábà Èyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ run pẹ̀lú igbe ní ọjọ́ ogun pẹ̀lú ìjì ní ọjọ́ ààjà Ọba wọn yóò sì lọ sí ìgbèkùn Òun àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀ lápapọ̀, ni Olúwa wí Ìdájọ́ tí Yóò Wá Sórí Ísírẹ́lì Èyí ni ohun tí Olúwa wí Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Móábù, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, Nítorí ó ti sun-ún, di eérú, egungun ọba Édómù Èmi yóò rán iná sí orí Móábù Èyí tí yóò jó àwọn ààfin Kéríótì run Móábù yóò sì kú pẹ̀lú ariwo pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè Èmi yóò ké onídájọ́ rẹ̀ kúrò Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ aládé rẹ́ nínú rẹ̀, ni Olúwa wí Èyí ni ohun tí Olúwa wí Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Júdà, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Nítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀ wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́ Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà Òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé Èmi yóò rán iná sí orí Júdà Èyí tí yóò jó àwọn ààfin Jérúsálẹ́mù run Èyí ni ohun tí Olúwa wí Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Ísírẹ́lì àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà wọ́n ta olódodo fún fàdákà àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn talákà mọ́lẹ̀ bí wọ́n ti ń tẹ ẹrùpẹ̀ ilẹ̀ tí wọ́n sì fi òtítọ́ du àwọn tí a ni lára Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúndíá kan náà Láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bá a pẹpẹ Lórí aṣọ tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́ ní ilé òrìṣà wọn wọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtanràn Mo pa àwọn ará Ámórì run níwájú wọn gíga ẹni tí ó dàbí igi Kédárì Òun sì le koko bí igi Óákù mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá àti egbò rẹ̀ láti ìṣàlẹ̀ wá Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, mo sì sìn yín la ihà já ní ogójì ọdún láti fi ilẹ̀ àwọn ará Ámórì fún un yín Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàárin àwọn ọmọ yín àti láàárin àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Násárátì èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Ísírẹ́lì ni Olúwa wí Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Násárátì ní ọtí mu Ẹ sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọ tẹ́lẹ̀ Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀ bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀ Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọ alágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀ jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là tafàtafà kì yóò dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó gún ẹṣin kì yóò gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọ yóò sálọ ní ìhòòhò ní ọjọ́ náà, ni Olúwa wí Ẹ̀rí Jíjẹ́ Nípa Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Éjíbítì Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ níyà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti gbà láti ṣe é Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbo, bí kò bá ní ohun ọdẹ Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀ bí kò bá rí ohun kan mú Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀ nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀ nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú, àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù Tí ewu bá wú ìlú kò ha ṣe Olúwa ni ó fà á Nítòótọ́ Olúwa Ọlọ́run kò ṣe ohun kan láìfi èrò rẹ̀ hàn sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀ Kìnnìún ti bú ramúramù ta ni kì yóò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ ta ni le ṣe àìsọtẹ́lẹ̀ Ẹ kéde ní ààfin Áṣídódù àti ní ààfin ní ilẹ̀ Éjíbítì Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samáríà Kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrin rẹ̀ àti ìnílára láàrin àwọn ènìyàn rẹ Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere, ni Olúwa wí, Ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀ Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run yóò wó ibi gíga yín palẹ̀ a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́ Èyí ni ohun tí Olúwa wí Bí olusọ-àgùntan ti ń gbà itan méjì kúrò ní ẹnu kìnnìun tàbí ẹ̀là eti kan bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí ń gbé Samáríà kúrò ní igun ibùsùn wọn ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Dámásíkù Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jákọ́bù, ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run alágbára Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Ísírẹ́lì lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Èmi yóò pa pẹpẹ Bétélì run ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò yóò sì wó lulẹ̀ Èmi yóò wó ilé òtútù lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ẹ̀ẹ̀rùn ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé a ó sì pa ilé ńlá náà run, ni Olúwa wí Ísírẹ́lì Kò Yípadà Sí Ọlọ́run Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin màlúù Báṣánì lórí òkè Samáríà, ẹ̀yin obìnrin tí ó ń ni talákà lára, tí ó ń tẹ aláìní mọ́lẹ̀, tí ó wí fún ọkọ rẹ̀, Gbé wá kí a sì mu! Olúwa Ọlọ́run ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra Àkókò náà yóò dé nítòótọ́ nígbà tí a ó fi ìwọ̀ mú un yín lọ, ẹni tí ó kẹ́yìn pẹ̀lú ìwọ̀ ẹja Ẹni kọ̀ọ̀kan yín yóò jáde lọ gba àárin odi yíya a ó sì lé e yín sí Hámónà, ni Olúwa wí Ẹ lọ sí Bétélì láti dẹ́ṣẹ̀ ẹ lọ sí Gílígálì kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí i Ẹ mú ẹbọ sísun yín láràárọ̀ wá, ìdámẹ́wàá yín ní ọdọdún mẹ́ta Kí ẹ mú ọrẹ́ ìdúpẹ́ ìyẹ̀fun tí a sun kí ẹ sì mú ọrẹ àtinúwá lọ fi wọ́n yagàn, ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, nítorí èyí ni ẹ fẹ́ láti ṣe, ni Olúwa Ọlọ́run wí Èmi fún un yín ní inú òfìfo ní gbogbo ìlú àti láìní àkàrà ní gbogbo ibùgbé yín, ṣíbẹ̀, ẹ̀yin kò tí ì yípadà sími, ni Olúwa wí Àti pẹ̀lú mo mú òjò dúró nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹ́ta Mo rán òjò sí ibùgbé kan ṣùgbọ́n kò rọ̀ sí ìlú mìíràn Oko kan ní òjò àwọn mìíràn kò ní ó sì gbẹ Àwọn ènìyàn ń rìn láti ìlú kan sí ibòmíràn fún omi wọn kò rí àrító láti mú, ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi, ni Olúwa wí Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo lu ọgbà àti ọgbà àjàrà yín mo fi àrá àti ìrì lù wọ́n Esú sì jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi ólífì yín, ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi, ni Olúwa wí Mo rán àjàkálẹ̀-àrùn sí i yín bí mo ti ṣe sí Éjíbítì Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín Pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí a kó ní ìgbékùn Mo kún imú yín fún òórùn ibùdó yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi, ni Olúwa wí Mo ti bì ṣubú nínú yín, bí Ọlọ́run ti bi Sódómù àti Gòmórà ṣubú ẹ̀yin sì dàbí ògúnná tí a fò yọ kúrò nínú ìjóná, ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi, ni Olúwa wí Nítorí náà, èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí i yín, Ísírẹ́lì, àti nítorí tí èmi ó ṣe èyí sí i yín, ẹ múra láti pàdé Ọlọ́run yín, ẹ̀yin Ísírẹ́lì Ẹni tí ó dá àwọn òkè tí ó dá afẹ́fẹ́ tí ó sì fi èrò rẹ̀ hàn sí ènìyàn, ẹni tí ó yípadà sí òkùnkùn tí ó sì tẹ ibi gíga ayé Olúwa Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo ni orúkọ rẹ̀ Wò Mí Kí O Sì Yè Gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ìpohùnréré ẹkún tí mo ṣe nípa rẹ Wúndíá Ísírẹ́lì ṣubú láì kò sì le padà dìde ó di ẹni ìkọ̀tì ní ilẹ̀ rẹ̀ kò sí ẹni tí yóò gbé e nàró Èyí ni ohun tí Olúwa ọ̀gá ògo wí Ìlú tí ẹgbẹ̀rún alágbára ti jáde, yóò dín ku ọgọ́run ní Ísírẹ́lì Ìlú tí ọgọ́run alàgbà ti jáde yóò ṣẹ́ku ẹni mẹ́wàá Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ilé Ísírẹ́lì Wá mi kí o sì yè Ẹ má ṣe wá Bẹ́tẹ́lì, Ẹ má ṣe lọ sí Gílígálì Ẹ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Bíáṣébà Nítorí dájúdájú a ó kó Gílígálì ní ìgbèkùn A ó sì sọ Bẹ́tẹ́lì di asán Ẹ wá Olúwa , ẹ̀yin yóò sì yè, Kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Jósẹ́fù A sì jó o run Bẹ́tẹ́lì kò sì ní rí ẹni tí yóò bomi pa á Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkorò Tí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀ Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Píláédì àti Óríónì Ẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀ Tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ Ẹni tí ó wọ́ omi òkun jọpọ̀ Tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀ Olúwa ni orúkọ rẹ̀, Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódi Tí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ aládé di ahoro Ìwọ kórìíra ẹni tí ń ṣòdì ní ẹnu ibodè ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́ Ìwọ ń tẹ talákà mọ́lẹ̀ o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn Nítorí mo mọ iye àìṣedédé rẹ mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ o sì ń fi òtítọ́ du talákà ní ilé ẹjọ́ Àwọn ọlọgbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí Nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́ Wá rere, má ṣe wá búburú kí ìwọ ba à le yè Nígbà náà ni Olúwa alágbára yóò wà pẹ̀lú ù rẹ Òun yóò sì wà pẹ̀lú ù rẹ bí ìwọ ṣe wí Kòrìírà búburú kí o sì fẹ́ rere Dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́ Bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára yóò síjú àánú wo ọmọ Jósẹ́fù tó ṣẹ́kù Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa , Ọlọ́run alágbára wí Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sunkún Àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà Nítorí èmi yóò la àárin yín kọjá, ni Olúwa wí Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́ nítorí ọjọ́ Olúwa kí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́ Yóò dàbí ọkùnrin tí ó sá láti ẹnu àmọ̀tẹ́kùn Tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu ẹkùn yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ tí ó simi lé ògiri ilé rẹ̀ tí ejò sì bù ú ṣán Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀ Tí ó sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀ Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àṣè ẹ̀sìn in yín Èmi kò sì ní inú dídùn sí àpèjọ yín Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ọrẹ sísun àti ọrẹ ọkà wá Èmi kò ní tẹ́wọ́n gbà wọ́n Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá Èmi kò ní náání wọn Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìn Èmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín Jẹ́ kí òtítọ́ ṣàn bí odò àti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wá ní ogójì ọdún ní ihà ìwọ ilé Ísírẹ́lì Ẹ̀yin ń gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín ibùgbé àwọn òrìṣà yín àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ, èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Dámásíkù, ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára Ègbé Ni Fún Àwọn Tí Ara Rọ̀ Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Síónì àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaríà àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì máa ń tọ̀ ọ́ wá Ẹ lọ Kálínì kí ẹ lọ wò ó Kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Ámátì ìlú ńlá a nì Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gátì ní ilẹ̀ Fílístínì Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju ti yín lọ bí Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú, ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòòsí Ẹ̀yin sùn lé ibusùn tí a fi eyín erin ṣe Ẹ sì tan ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn Ẹ̀yin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn yín jẹ Ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrin agbo wọn jẹ Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dáfídì Ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ̀ àwọn ohun èlò orin Ẹ̀yín mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan àti ìkunra tí o dára jùlọ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káànú ilé Jósẹ́fù tí o di ahoro Nitorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn àwẹ̀jẹwẹ̀mú àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò Olúwa ọ̀gá ògo ti búra fúnra rẹ̀ Olúwa Ọlọ́run alágbára sì ti wí pé Mo kórìíra ìgbéraga Jákọ́bù n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀ Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀ Bí Ọkùnrin mẹ́wàá bá sẹkù nínú ile kan, àwọn náà yóò kú Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béérè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó farapamọ́ níbẹ̀, Njẹ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín tí ó bá sì dáhùn wí pé, Rárá, nígbà náà ni yóò wí pé, Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà, Oun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú Àti sísán kọlu ilé kékèké Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi ẹṣin kọ́ ni lórí àpáta bí Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí ọ̀títọ́ padà sí májèlé Ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lódábárì Ẹ̀yin sì wí pé, Ṣé kì í se agbára wa ni àwa fi gba Kánáímù Nítorí Olúwa Ọlọ́run alágbára wí pé, Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Ísírẹ́lì, tí yóò máa ni ọ́ lára ní gbogbo ọ̀nà láti ẹnu ọ̀nà ìwọlé Hámátì títí dé àfonífojì aginjù Eṣú, Iná Àti Ìwọ̀n Okùn Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run fi hàn mí Ó pèsè ọwọ́ esú lẹ́yìn ìgbà tí a kórè ìpín ọba, ní ìgbà ti èso ẹ̀ẹ̀kejì ń jáde bọ̀ Nígbà tí wọ́n jẹ koríko ilẹ̀ náà mọ́ féfé nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ ọ́, dáríjìn! Báwo ni Jákọ́bù yóò ha ṣe lè dìde Òun kéré jọjọ! Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí Èyí kò ni sẹlẹ̀, ni Olúwa wí Èyí ni ohun ti Olúwa Ọlọ́run fi hàn mí Olúwa Ọlọ́run ń pè fún ìdájọ́ pẹ̀lú iná ó jó ọ̀gbun ńlá rún, ó sì jẹ ilẹ̀ run Nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, Olúwa Ọlọ́run jọ̀wọ́ má ṣe ṣe é! Báwo ni Jákọ́bù yóò ha ṣe lè dìde Òun kéré jọjọ! Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀, ni Olúwa alágbára wí Èyí ni ohun tí ó fi hàn mí Olúwa dúró ní ẹ̀gbẹ́ odi ti a fi okùn ìwọ̀n mọ́, ti òun ti okùn-ìwọ̀n tí ó rún ni ọwọ́ rẹ̀ Olúwa sì bi mi pé, Ámósì, kí ni ìwọ rí Mo dáhùn pé, Okùn-ìwọ̀n Nígbà náà ni Olúwa wí pé, Wòó, Èmí ń gbé okùn-ìwọ̀n kalẹ láàárin àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi Èmi kì yóò sì tún kọjá lọ́dọ̀ wọn mọ́ Ibi gíga Ísáákì wọ̀n-ọn-nì yóò sì di ahoro àti ibi mímọ Ísírẹ́lì wọ̀n-ọn-nì yóò di ahoro Èmi yóò sì fi idà dide sí ilé Jéróbóámù Nígbà náà Ámásáyà àlùfáà Bẹ́tẹ́lì ránṣẹ́ sí Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, wí pé Ámosì ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárin gbùngbùn Ísírẹ́lì Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ Nítorí èyí ni ohun ti Ámosì ń sọ  Jéróbóámù yóò ti ipa idà kú, Lóótọ́ Ísírẹ́lì yóò lọ sí ìgbèkùn, jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn   Nígbà náà ni Ámásáyà sọ fún Ámósì pé Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Júdà Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀ ki o sì sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀ Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Bẹ́tẹ́lì nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹ́ḿpìlì ìjọba rẹ̀ Ámósì dá Ámásáyà lóhùn pé, Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùsọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, Lọ sọtẹ́tẹ̀ fun àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ ọ̀rọ̀ Olúwa Ìwọ wí pé,  Má ṣe sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí Ísírẹ́lì Má ṣì ṣe wàásù sí ilé Ísáákì Nítorí náà, èyí ni ohun ti Olúwa wí  Ìyàwó rẹ yóò di paṣángà ni ìlú, àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú A ó wọn ilẹ̀ rẹ, a ó sì pín in àti ìwọ pẹ̀lú yóò kú ni ilẹ̀ àìmọ́ Ísírẹ́lì yóò sì lọ sí ìgbèkùn, kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn   Agbọ̀n Èso Pípọ́n Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run fi hàn mi agbọ̀n èso pípọ́n Ó béèrè pé, Ámósì kí ni ìwọ rí Mo sì dáhùn pé, Agbọ̀n èso pípọ́n Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́ Olúwa Ọlọ́run wí pé, Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹ́ḿpìlì yóò yí padà sí ohùnréré ẹkún Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú-ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́! Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba, tí ẹ sì ń sọ talákà di ilẹ Tí ẹ ń wí pé, Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí kí àwa bá à lè ta ọkà kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin kí àwa bá à le ta jéró Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á kí a sì fi òṣùnwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ Kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn talákà kí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìní kí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀ Olúwa ti fi ìgbéraga Jákọ́bù búra pé Èmi kì yóò gbàgbé ọkan nínú ohun tí wọ́n ṣe Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kì yóò ha wárìrì fún èyí Àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ kì yóò ha sọ̀fọ̀ Gbogbo ilẹ̀ yóò ru sókè bí omi Náílì, yóò sì ru ú sókè pátapáta bí ìkún omi a ó sì tì í jáde, a ó sì tẹ̀ ẹ́ rì gẹ́gẹ́ bí odò Éjíbítì Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ni Olúwa Ọlọ́run wí, Èmi yóò mú òòrùn wọ̀ ní ọ̀sán, Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀ṣán gangan Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀, gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí a sì fá orí i yín Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí a bí àti opin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò Ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa Ọlọ́run wí, nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òùngbẹ fún omi Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Àwọn ènìyàn yóò rìn kiri láti òkun dé òkun wọn yóò sì máa rìn ká láti gúṣù sí àríwá, wọn yóò máa wá ọ̀rọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i Ní ọjọ́ náà àwọn arẹwà wúndíá àti àwọn alágbára ọ̀dọ́mọkùnrin yóò dákú fún òùngbẹ omi Àwọn tí ó fi òrìṣà Samaríà búra tí wọ́n wí pé, tí wọ́n sì wí pé, ìwọ Dánì, ọlọ́run rẹ ń bẹ láàyè, àti bi ó ti dájú pé ọlọ́run Báṣébà ti ń bẹ láàyè àní, wọn yóò ṣubú, wọn kì yóò sì tún dìde mọ́ láàyè ìwọ Dánì Bí ó ti dájú pè ọlọrun rẹ ń bẹ láàyè ìwọ Báṣébà Wọ́n yóò ṣubú, Wọn kì yóò si tún díde mọ A Ó Pa Ísírẹ́lì Run Mo rí Olúwa , ó dúró ní ẹ̀bá pẹpẹ, ó sì wí pé Lu orí àwọn àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn kí àwọn òpó kí ó lè mì fọ́ wọn sí orí àwọn gbogbo ènìyàn àwọn tí ó sẹ́kù ni èmi yóò fi idà pa, Ẹni tí ó sálọ nínú wọn kí yóò sá gbé Ẹni ti ó sá àsálà nínú wọn kí yóò gbàlà Bí wọ́n tilẹ wa ilẹ lọ sí ìpò òkú Láti ibẹ̀ ni ọwọ́ mi yóò ti tẹ̀ wọ́n Bí wọ́n tilẹ̀ gun òkè ọ̀run lọ, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú wọn sọ̀kalẹ̀ Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara wọn pamọ́ ni orí òkè Kámẹ́lì, èmi yóò wá wọn rí, Èmi yóò si mú wọn kúrò níbẹ̀ Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara pamọ́ fún mi sí ìṣàlẹ̀ òkun, láti ibẹ̀ ni Èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò kí ó bù wọ́n ṣán Bí wọ́n tilẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní iwájú àwọn ọ̀tá wọn láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti pàṣẹ fún idà kí ó ṣá wọn pa Èmi yóò sì tẹ ojú mi mọ́ wọn fún ìbí, kì í sì í se fún rere Olúwa , Ọlọ́run Alágbára Ẹni ti ó fi ọwọ́ kan ìlẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì sọ̀fọ̀ Gbogbo orílẹ̀ èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Náìlì ti wọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Éjíbítì Òun ni ẹni tí ó kọ́ itẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run ti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayé Ẹni ti ó pe àwọn omi òkun ti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé Olúwa ni orúkọ rẹ̀ Àbá ẹyin ọmọ Ísírẹ́lì kò ha dàbí àwọn ọmọ Kúsì sí mi ni Olúwa wí Èmi kò ha ti mú Ísírẹ́lì gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì jáde wá àti àwọn Fílístínì láti ilẹ̀ Káfítórì àti àwọn Árámú láti kírì Dájúdájú, ojú Olúwa Ọlọ́run ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀ Ṣíbẹ̀ Èmi kò ni pa ilé Jákọ́bù run pátapáta, ni Olúwa wí Nítorí Èmi yóò pàṣẹ, Èmi yóò sì mi ilé Ísírẹ́lì ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè bí a ti ń jọ ọkàn nínú ajọ̀ tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀ Gbogbo àwọn ẹlẹ́sẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn mi ni yóò ti ipa idà kú gbogbo àwọn ti ń wí pé Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́ A mú Ísírẹ́lì padà bọ̀ sípò Ní ọjọ́ náà ní Èmi yóò gbé àgọ́ Dáfídì tí ó wó ró Èmi yóò mọ odi rẹ̀ tí ó wó Èmi yóò sì sọ ahoro rẹ̀ di ìlú Èmi yóò sì kọ bí ó ti wà tẹ́lẹ̀ kí wọn le jógun ìyókù Édómù àti gbogbo orílẹ̀ èdè ti ń jẹ́ orúkọ mi, ni Olúwa , ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí Ọjọ́ náà ń bọ, ni Olúwa wí, Tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀ Tí yóò sì ṣàn láti ara àwọn òkè kékèké Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Ísírẹ́lì ènìyàn mi padà bọ̀ Wọn yóò sì kọ́ ahoro ìlú, wọn yóò sì máa gbé inú wọn Wọn yóò sì gbin àjàrà, wọn yóò sì mu ọtí wáìnì wọn wọn yóò sì se ọgbà pẹ̀lú, wọn yóò sì jẹ èso inú wọn Èmi yóò gbin Ísírẹ́lì sí orí ilẹ̀ rẹ̀ A kì yóò sì fà wọn tu mọ́ láéláé kúrò ni orí ilẹ̀ ti mo fi fún wọn, ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wí Àwọn Ọpẹ́ Àti Àdúrà Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì Jésù Kírísítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Tìmótíù arákùnrin wa Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin nínú Kírísítì tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kólósè Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún-un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa Nígbàkúùgbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Kírísítì, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń ṣàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìnrere náà tí ó ti wá sọ́dọ̀ yín Káàkiri àgbáyé ni ìyìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrin yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ ọ́, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀ Ẹ̀yin ti kọ́ ọ lọ́dọ̀ Épáfúrà, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa olùfẹ́, ẹni tí ó jẹ́ olótìtọ́ ìránṣẹ́ Kírísítì ní ipò wa ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò yéé gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípaṣẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹlẹ́gbẹ́ irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà ninú ìmọ̀ Ọlọ́run pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀ṣíwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀ Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yin láti jẹ́ alábàápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀ Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, ìdàríjì ẹ̀sẹ̀ Kírísítì ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá Nítorì nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ sọ̀kan Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí Òun lè ní ipo tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun lè máa gbé nínú rẹ̀ Àti nípaṣẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ lọ́rùn, nípa mímú àlàáfíà wá nípaṣẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélèbùú Ẹ̀yin ya ara yín nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà kan rí, ẹ jẹ́ ọ̀tá nínú ọkàn yín nítorí ìwà búburú yín Ṣùgbọ́n nísinsìnyìí, ó ti mú yín padà nípa ara rẹ̀ nìpa ikú láti mú un yín lọ sí iwájú rẹ̀ ní mímọ́, aláìlábàwọ́n àti aláìlábùkù Bí ẹ̀yin bá dúró nínú ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ fesẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ sì dúró sinsin, láláìyẹṣẹ̀ kúrò nínú ìrètí ti ìyìnrere ti ẹ̀yin ti gbọ́, èyí tí a ti wàásù rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lábẹ́ ọ̀run, àti èyí ti èmi Pọ́ọ̀lù ṣe ìránṣẹ́ fún Nísinsinyìí èmi ń yọ̀ nínú ìjìyà fún un yín Inú mi sì dùn, nítorí mo ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti jẹ ìyà tó ṣẹ́kù nínú ìyà Kírísítì fún ara rẹ̀, èyí tí ì ṣe ìjọ Nínú èyí tí a fi ṣe ìránṣẹ́ fún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run tí a fifún mi fún yín láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ Ó ti pa àsírí ìjìnlẹ̀ yìí mọ́ fún ayérayé àti láti ìrandíran Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ó ti fihàn fún àwọn ẹni mímọ́ Àwọn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti fi hàn kí ni títóbi láàrin àwọn aláìkọlà, ní ọ̀rọ̀ ògo ohun ìjìnlẹ̀ yìí, èyí tí í ṣe Kírísítì ìrétí ògo nínú yín Àwa ń wàásù rẹ̀, a ń gbani níyànjú a sì ń kọ olúkúlùkù ènìyàn ní ọgbọ́n gbogbo, kí a lè mú olúkúlùkù dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní pípé nínú Kírísítì Sí èyí sì ni èmi ń ṣe làálàá, ti mo sì ń làkàkà pẹ̀lúgbogbo agbára rẹ̀, èyí tó ń sisẹ́ nínú mi Òmìnira Kúrò Lọ́wọ́ Òfin Ènìyàn Nípa Ààyè Pẹ̀lú Kírísítì Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń jìjàkadì fún un yín àti fún àwọn ará Laodékíà àti fún ọ̀pọ̀ ènìyàn mìíràn tí wọn kò ì tí ì rí mi sójú rí Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ lè ní ìjìnlẹ̀ ìrírí ìmọ́ Kírísítì pẹ̀lú òye àti ìmọ̀ tó dájú ṣáká Nítorí nísinsinyìí, Ọlọ́run ti fi àṣírí ètò hàn Ìjìnlẹ̀ àṣírí ètò náà ni Kírísítì fúnrarẹ̀ Nínú ẹni tí a fi gbogbo ìsùra ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀ pamọ́ sí Mo sọ èyí fún un yín kí ẹnikẹ́ni ma baà fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn mú yín sìnà Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí i lọ́dọ̀ yín nínú ara, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ni mo sì ń yọ̀ láti kíyèsí ètò yín àti bí ìdúró sinsin yín nínú Kírísítì ti rí Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jésù Kírísítì gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀ Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé e yín ró nínú rẹ̀, ẹ máa se alágbára nínú ìgbàgbọ́, bí a ti ṣe kọ́ ọ yín, àti kí ẹ sì máa ṣàn bí omi pẹ̀lú ọpẹ́ Ẹ máa kiyesii pé ẹnikẹ́ni kò fi ìmọ̀ àti ẹtan asan ko yín ní ìgbèkùn, èyí tí ó jẹmọ́ ìtàn ènìyàn bi ìpilẹ̀sẹ ẹ̀kọ́ ayé láìse ohun tí Kírísítì ti wí Nítorí nínú Kírísítì ni àti rí ẹ̀kún ìwà Ọlọ́run ní ipò ara, ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kírísítì, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ Nínú ẹni tí a kò fí ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní Ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kírísítì Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípaṣẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú Àti ẹ̀yin, ẹni tí o ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ni, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn-án a mọ àgbélébùú Ó sì ti já àwọn aláṣẹ àìrí àti àwọn alágbára, ó ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn nínú rẹ̀ Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àṣẹ, tàbí oṣù titun, àtì ọjọ́ ìsinmi Àwọn tí í ṣe òjìjí ohun tí ń bọ̀ ṣùgbọ́n ti Kírísítì ni ara Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó inú dídùn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èké àti bíbọ àwọn ańgẹ́lì lọ́ èrè yín gbà lọ́wọ́ yín, ẹni tí ń dúró lórí nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí ó ti rí, tí ó ń ṣe féfé asán nipa èrò ti ọkan ara rẹ̀ Tí kò sì di orí nì kú ṣinṣin, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí a ń ti ipa oríkèé àti iṣan pèsè fún gbogbo ara, ti a sì ń so ó ṣọ́kan pọ̀, tí ó sì ń dàgbà nípa ìmísí Ọlọ́run Bí ẹ̀yin bá ti kú pẹ̀lú Kírísítì kúrò nínú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, èé ha ti ṣe tí ẹ̀yin ń tẹ́ríba fún òfin bí ẹni pé ẹ̀yin wà nínú ayé, Má ṣe dìímú, má se tọ́ ọ wò, má ṣe fọwọbàá, Gbogbo èyí tí yóò ti ipa lílo run, gẹ́gẹ́ bí òfin àti ẹ̀kọ́ ènìyàn Àwọn nǹkan tí ó ní àfarawé ọgbọ́n nítòótọ́, ni àdábọwọ́ ìsìn, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti ìpọn-ara-lójú, ṣùgbọ́n tí kò ni èrè hàn nínú fún ìfẹ́kúfẹ ara Àwọn Òfin Fún Ìgbé Ayé Ìwàmímọ́ íwọ̀n ìgbà tí a ti jí yín dìde pẹ̀lú Kírísítì ẹ máa ṣafẹrí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbi tí Kírísítì gbé wà tí ó jòkòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lóké kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé Nítorí ẹ̀yín ti kú, a sì fi iyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kírísítì nínú Ọlọ́run Nígbà tí Kírísítì, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyìí jásí ìbọ̀rìsà Lórí àwọn wọ̀nyìí ni ìbínú Ọlọ́run ńbọ̀ wá Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apákan ayé yìí Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyìí sílẹ̀ ìbínú, ìrúnú, àránkan, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ayé yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀, tí ẹ sì ti gbé ìgbé ayé titun wọ̀, èyí tí a sọ di titun nínú ìmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ẹni tí ó dáa Níbi tí kò gbé sí Gíríkì tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìnímọ̀, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kírísítì ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo Nítorí náà, bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, ẹni mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìsoore, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù àti sùúrù Ẹ máa fara dàá fún ara yín, ẹ sì máa dáríji ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan bí Kírísítì ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan kí ẹ sì máa dúpẹ́ Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kírísítì máa gbé inú yín lí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo kí ẹ sì máa gba ara yín, níyànjú nínú Sáàmù, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa fi oore ọ̀fẹ́ kọrin ní ọkàn yín sí Olúwa Ohunkóhun tí ẹ̀yín bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jésù Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run baba nípasẹ̀ rẹ̀ Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fẹ́ràn àwọn aya yín, ẹ má sì ṣe korò sí wọn Ẹ̀yin ọmọ ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín ní ohun gbogbo nítorí èyí dára gidigi nínú Olúwa Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo kì í ṣe ní àrojú ṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn ṣugbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn Kí ẹ mọ̀ pé lọ́wọ́ Olúwa ni ẹ̀yin ó gba èrè ogun nítorí ẹ̀yin ń sìn Olúwa Kírísítì Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àìṣòdodo, yóò gbàá padà nítorí àìṣòdodo náà tí ó ti ṣe kò sì sí ojúṣáájú Àwọn Ìlànà fún Ìjọ Ẹyin olúwa, ẹ má a fi èyí tí ó tọ́ tí ó sì dọ́gba fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ yín kí ẹ sì mọ̀ pé ẹ̀yin pẹ̀lú ni owa kan ní ọ̀run Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́ Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣílẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kírísítì, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú Ẹ gbàdúrà pé kí èmí leè máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi Ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n ni tí bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ńbẹ̀ lóde, kí ẹ sì máa ra ìgbà padà Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá òlúkulùlku ènìyàn lóhùn Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikíkú yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀ gbogbo bí nǹkan tirí nípa mi Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòótọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa Ẹni tí èmí ń rán sí yín ńitorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọ̀kàn yín nínú Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Ónísímù, arákùnrin olóòótọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín-yìí fún un yín Árísítákù, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Máàkù, ọmọ arábìnrin Bánábà Àti Jésù, ẹni tí à ń pè ní Jọsítọ́sì, ẹni tí ń ṣe ti àwọn onílà Àwọn wọ̀nyí nìkan ni olùbá ṣiṣẹ́ mí fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹni tí ó tí já sí ìtùnú fún mi Épáfúrà, ẹni tí ń ṣe ọ̀kan nínú yín àtiìránṣẹ́ Kírísítì kí í yín Òun fí ìwàyájà gbàdúrà nígbà gbogbo fún-ún yín, kí ẹ̀yin kí ó lè dúró ní pípé nínú ohun gbogbo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run Nítorí mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń ṣisẹ́ kárakára fún yín, àti fún àwọn tí ó wà ní Laodékíà, àti àwọn tí ó wà ní Hírápólì Lúùkù, aràkùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn, àti Dẹ́mà ki í yín Ẹ kí àwọn ará tí ó wà ńi Laodékíà, àti Nímífásì, àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀ Nígbà tí a bá sì ka ìwé yìí ní àárin yín tan, kí ẹ mú kí a kà á pẹ̀lú nínú ìjọ Laodékíà ẹ̀yin pẹ̀lú sì ka èyí tí ó ti Laodékíà wá Kí ẹ sì wí fún Áríkípù pé, Kíyèsi iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ìwọ ti gbà nínú Olúwa kí o sì ṣe é ní kíkún Ìkíni láti ọwọ́ èmi Pọ́ọ̀lù Ẹ máa ránti ìdè mi Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú yín Àmín A kọ ọ́ láti Rómù lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Kólósè láti ọwọ́ Tíkíkù àti Ónísímù Ẹ̀kọ́ Dáníẹ́lì Ní Bábílónì Ní ọdún kẹta tí Jéhóíákímù jẹ ọba Júdà, Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù, ó sì kọ lù ú pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ Olúwa sì fa Jéhóíákímù ọba Júdà lé e lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó lọ sí ilé òrìṣà ní Bábílónì, sí inú ilé ìṣúra òrìṣà a rẹ̀ Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Áṣípénásì, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò ní àbùkù ara, tí wọ́n rẹwà, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ hàn, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí òye tètè ń yé àti àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba kí ó kọ́ wọ́n ní èdè àti onírúurú ẹ̀kọ́ ìwé ti àwọn Bábílónì Ọba pèsè oúnjẹ ojoojúmọ́ àti wáìnì láti orí tábìlì i rẹ̀ fún wọn, ó sì kọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta Lẹ́yìn náà ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ fún ọba Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó wá láti Júdà Dáníẹ́lì, Hananíáyà, Mísáẹ́lì àti Ásáríyà Olórí àwọn ìwẹ̀fà fún wọn ní orúkọ tuntun Ó fún Dáníẹ́lì ní Beliteṣáṣárì, ó fún Hananíáyà ní Sádírákì, ó fún Mísáẹ́lì ní Mésákì àti Áṣáríyà ní Àbẹ́dinígò Ṣùgbọ́n Dáníẹ́lì pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun kò ní ba ara òun jẹ́ pẹ̀lú oúnjẹ àti wáìnì ọba, nígbà náà ni ó gba ààyè lọ́wọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà wí pé òun kò fẹ́ ba ara òun jẹ́ ní ọ̀nà yìí Ọlọ́run mú kí Dáníẹ́lì rí ojúrere àti àánú gbà láti ọwọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà, Ṣùgbọ́n olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ fún Dáníẹ́lì pé, Mo bẹ̀rù Olúwa mi, ẹni tí o ti pèṣè oúnjẹ àti ohun mímu rẹ Báwo ni ìrísí ì rẹ yóò ṣe burú jù ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ rẹ lọ Nígbà náà ni èmi yóò fi orí mi wéwu lọ́dọ̀ ọba Nígbà náà ni Dáníẹ́lì sọ fún olùṣọ́ tí olórí àwọn ìwẹ̀fà yàn lórí i Dáníẹ́lì, Hananiáyà, Mísáẹ́lì àti Ásáríyà pé, Jọ̀wọ́ dán àwa ìránṣẹ́ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá Má ṣe fún wa ní ohun kankan, àfi ẹ̀fọ́ láti jẹ àti omi láti mu Nígbà náà ni kí o fi ìrísí i wa wé ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba, kí o sì ṣe àwa ìránṣẹ́ rẹ ní ìbámu pẹ̀lú u bí o bá ṣe rí i sí Bẹ́ẹ̀ ni ó sì gbà láti dán wọn wò fún ọjọ́ mẹ́wàá Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwàá ara wọn le, wọ́n sì sanra ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba lọ Bẹ́ẹ̀ ni olùṣọ́ mú oúnjẹ àdídùn àti wáìnì tí ó yẹ kí wọ́n mu kúrò, ó sì fún wọn ní ẹ̀fọ́ dípò rẹ̀ Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ní ìmọ̀ àti òyé nínú un gbogbo onírúurú ìwé àti ẹ̀kọ́ ọ wọn Dáníẹ́lì sì ní òyé ìran àti àlá ní oríṣìíríṣìí Ní òpín ìgbà tí ọba dá, pé kí a mú wọn wá sínú ààfin, olórí àwọn ìwẹ̀fà mú wọn wá ṣíwájú ọba Nebukadinésárì Ọba sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì rí i pé kò sí ẹni tí ó dàbí i Dáníẹ́lì, Hananíáyà, Míṣáẹ́lì àti Ásáríyà Nítorí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ọba Nínú un gbogbo ọ̀ràn, ọgbọ́n àti òyé tí ọba ń bèrè lọ́wọ́ ọ wọn, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn amòye àti ọlọ́gbọn tí ó wà ní gbogbo ìjọba rẹ̀ Dáníẹ́lì sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kìn-ín-ní ọba Kírúsì Dáníẹ́lì Rí Ìran Ọkùnrin Kan Ní ọdún kẹta Sárúsì ọba Páṣíà, a fi ìran kan hàn Dáníẹ́lì Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ ìran náà, ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àsìkò ìpọ́njú ńlá, òye ọ̀rọ̀ náà wá bá a nínú ìran Ní àsìkò náà, èmi Dáníẹ́lì ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta Èmi kì í jẹ oúnjẹ tí ó dára, èmi kò fi ẹran tàbí wáìnì kan ẹnu mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi òróró para títí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta fi kọjá Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù àkọ́kọ́, bí mo ti dúró sí etí i bèbè odò ńlá Tígírísì, Mo wo òkè, mo rí ọkùnrin kan tí ó wọ aṣọ àlà funfun, pẹ̀lú àmùrè wúrà dáradára ni ó fi di ẹ̀gbẹ́ Ara rẹ̀ dàbí báálì, ojú u rẹ̀ dàbí mọ̀nàmọ́ná, ẹyin ojú u rẹ̀ dàbí iná àtẹ̀tàn, apá àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ dàbí ìtànná ìmọ́lẹ̀ tí o kún fún idẹ, àti ohùn rẹ̀ dàbí i ti ìjọ ènìyàn púpọ̀ Èmi Dáníẹ́lì, ni ẹnìkan tí ó rí ìran náà, àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú u mi, wọn kò rí i, ṣùgbọ́n ìpayà ńlá dà bò wọ́n, wọ́n sálọ wọ́n sì fi ara pamọ́ Ó sì ku èmi nìkan, tí mo rí ìran ńlá yìí, kò sì ku ohun kankan fún mi, ojú u mi sì rẹ̀wẹ̀sì gidigidi, n kò sì ní agbára mọ́ Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, bí mo ṣe tẹ́tí sílẹ̀ síi, mo ṣùn lọ fọnfọn, ní ìdojúbolẹ̀ Ọwọ́ kan kàn mí, ó gbé mi dìde ní ìwárìrì lórí ọwọ́ àti eékún mi Ó sọ pé, Dáníẹ́lì ẹni tí a yànfẹ́ gidigidi gba ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ yìí yẹ̀wò dáadáa, kí o sì dìde, nítorí tí a rán mi sí ọ Bí ó ṣe sọ èyí fún mi, mo dìde ní ìwárìrì Nígbà náà ni ó tẹ̀ṣíwájú, pé, Má ṣe bẹ̀rù Dáníẹ́lì Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fi ọkàn rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì wá nítorí ọ̀rọ̀ náà Ṣùgbọ́n ọmọ aládé ìjọba Páṣíà dá mi dúró fún ọjọ́mọ́kànlélógún Nígbà náà ni Máíkẹ́lì, ọ̀kan lára ìjòyè àwọn ọmọ aládé, wá láti ràn mi lọ́wọ́, nítorí a dá mi dúró níbẹ̀ pẹ̀lú ọba Páṣíà Ní ìsinsinyí mo wá láti ṣàlàyé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú, nítorí ìran náà ń sọ nípa ọjọ́ iwájú Bí ó sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún mi, mo sì dorí kodò mo sì dákẹ́ Nígbà náà, ni ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kan ètè mi, mo la ẹnu mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ọ̀rọ̀, mo sọ fún ẹni tí ó dúró níwájú mi, Ìrònú sì mú mi, nítorí ìran náà, Olúwa mi, n kò sì ní okun Ǹjẹ́ báwo ni èmi ìránṣẹ́ ẹ̀ rẹ ṣe lè bá ọ sọ̀rọ̀, Olúwa mi Agbára mi ti lọ, agbára káká ni mo fi ń mí Ẹ̀wẹ̀, ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi ní agbára Ó sì wí pé, Má se bẹ̀rù, ìwọ ọkùnrin tí a yàn fẹ́ gidigidi Bí ó ti sọ̀rọ̀ fún mi, ara à mí sì le, mo sọ pé, Má a wí Olúwa mi, níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní agbára Nígbà náà, ni ó wí pé, Sé o mọ ìdí tí mo fi tọ̀ ọ́ wá Láìpẹ́ èmi yóò yípadà lọ bá àwọn ọmọ aládé Páṣíà jà, nígbà tí mo bá lọ àwọn ọmọ aládé Gíríkì yóò wá ṣùgbọ́n ní àkọ́kọ́, èmi yóò sọ ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé òtítọ́ fún ọ Ní ìsinsìnyí, mo sọ òtítọ́ fún ọ ọba mẹ́ta yóò dìde sí i ní Páṣíà, àti ẹ̀kẹrin tí yóò jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju gbogbo wọn lọ Tí ó bá ti di alágbára nípa ọrọ̀ rẹ̀, yóò sì ru gbogbo wọn sókè lòdì sí ìjọba Gíríkì Nígbà náà ni ọba alágbára kan yóò fara hàn, yóò ṣe àkóso pẹ̀lú agbára ńlá, yóò sì ṣe bí ó ti wù ú Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá fi ara hàn tán, ìjọba rẹ̀ yóò fọ́, yóò sì pín sí mẹ́rin ní origun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, ìjọba náà kò sì sọ́wọ́ àwọn ìran rẹ̀ tàbí kí ó ní agbára tí ó ń lò tẹ́lẹ̀, nítorí, a ó fa ìjọba rẹ̀ tu a ó sì fi fún àwọn mìíràn Ọba ìhà Gúṣù yóò di alágbára ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ rẹ̀ yóò di alágbára jùú lọ, yóò sì ṣe àkóso ìjọba rẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá Lẹ́yìn ọdún púpọ̀ wọn yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà, ọmọbìnrin ọba gúṣù yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ọba àríwá láti bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n òun kì yóò lè di agbára apá a rẹ̀ mú, bẹ́ẹ̀ ni òun kì yóò lè dá dúró, ṣùgbọ́n a ó tẹrí i rẹ̀ ba àti àwọn tí ó mú un wá, àti ọmọ tí ó bí, àti ẹni tí ó ń mu lọ́kàn le ní gbogbo àkókò wọ̀nyí Ọ̀kan lára àwọn ìdílé e rẹ̀, ọmọbìnrin ọba Gúṣù yóò dìde láti gba ipò o rẹ̀ Yóò sì kọ lu ogun ọba àríwá, yóò sì wọ́ odi alágbára yóò bá wọn jà yóò sì borí Yóò gba òrìṣà wọn, ère dídá àti ohun èlò oníye lórí ti fàdákà àti ti wúrà, yóò sì kó wọn lọ sí Éjíbítì Fún ọdún díẹ̀ yóò fi ọba àríwá lọ́rùn sílẹ̀ Nigbà náà, ni ọba àríwá yóò gbógun ti ilẹ̀ ọba, Gúṣù, ṣùgbọ́n yóò padà sí orílẹ̀ èdè Òun fúnra rẹ̀ Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò múra ogun wọn yóò kó ogun ńlá jọ, èyí tí a ó gbá lọ bí àgbàrá omi ńlá, yóò sì gbá a lọ títí dé ìlú olódi rẹ̀ Nígbà náà ni ọba Gúṣù yóò jáde pẹ̀lú ìbínú, yóò sì bá ọba àríwá jà, ẹni tí yóò kó ọmọ ogun púpọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ọba Gúṣù yóò borí i wọn Nígbà tí a bá kó ogun náà lọ, ọba Gúṣù yóò kún fún agbára, yóò sì pa ẹgbẹgbẹ̀rún ní ìpakúpa ṣíbẹ̀ kì yóò ṣẹ́gun Nítorí ọba àríwá yóò lọ kó ogun mìíràn jọ, tí ó pọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, yóò jáde pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun tí ó ti dira ogun fún dáradára Ní àkókò ìgbà náà, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò dìde sí ọba Gúṣù Àwọn ọlọ̀tẹ̀ nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò ṣọ̀tẹ̀ ní ìmúṣẹ ìran náà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí Nígbà náà ni ọba àríwá yóò wá yóò sì gbé ogun tìí, yóò sì kó ìlú olódi Ogun ọba Gúṣù kò ní ní agbára láti kọjú ìjà sí i Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọ̀wọ́ ogun tó dára jù kò ní ní agbára láti dúró Ẹni tí ó gbógun tìí yóò máa ṣe bí ó ti wù ú, kò sì sí ẹni tí yóò le è dojú kọ ọ́ Yóò sì fún ara rẹ̀ ní ibùjókòó ní ilẹ̀ tí ó dára, yóò sì ní agbára láti bàá jẹ́ Yóò pinnu láti wá pẹ̀lú agbára ìjọba rẹ̀, yóò sì ní májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú ọba Gúṣù yóò sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún-un láti fẹ́ ẹ ní ìyàwó nítorí kí ó lè gba ìjọba, ṣùgbọ́n ète rẹ̀ yìí kì yóò ṣiṣẹ tàbí se ìrànlọ́wọ́ fún-un Nígbà náà ni yóò yí ara padà sí ilẹ̀ etí òkun, yóò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n aláṣẹ kan yóò mú òpin bá àfojúdi rẹ̀, yóò sì yí àfojúdi rẹ̀ padà sí orí i rẹ̀ Lẹ́yìn èyí, yóò sì yí padà sí ìlú olódi ti orílẹ̀-èdè òun fún ra rẹ̀, ṣùgbọ́n yóò kọsẹ̀ yóò sì burú, a kì yóò sì ríi mọ́ Arọ́pò rẹ̀ yóò rán agbowó orí kan jáde láti fi ìdí ipò ọlá ọba múlẹ̀ ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n ọdún díẹ̀, a ó pa á run, kì yóò jẹ́ nípa ìbínú tàbí nínú ogun Ẹni tí kò níláárí kan yóò rọ́pò rẹ̀, ẹni tí a kò tí ì fi ọlá ọba fún rí Yóò sì gbógun sí ìjọba nígbà tí ọkàn àwọn ènìyàn balẹ̀ láìbẹ̀rù, yóò sì gbà á pẹ̀lú àrékérekè Nígbà náà, ni a ó gbà ogunlọ́gọ̀ ogun kúrò níwájú u rẹ̀, pẹ̀lú òun àti ọmọ aládé ti májẹ̀mu náà ni a ó parun Lẹ́yìn tí ó wá ṣe ìpinnu pẹ̀lú u rẹ̀, yóò hùwà ẹ̀tàn, pẹ̀lú iwọ̀nba ènìyàn kékeré ni yóò gba ìjọba Nígbà tí àwọn agbègbè tí ó lọ́rọ̀ gidigidi wà láìbẹ̀rù ni yóò gbógun tì wọ́n, yóò ṣe ohun tí baba rẹ̀ tàbí baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí, yóò pín ìkógún ẹrù àti ọrọ̀ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn in rẹ̀ Yóò pète àti bi àwọn ìlú olódi ṣubú, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀ ni Pẹ̀lú ogun púpọ̀, yóò sì ru agbára rẹ̀ àti ìgboyà rẹ̀ ṣókè sí ọba Gúṣù Ọba Gúṣù yóò dìde ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun tí ó lágbára gidigidi, ṣùgbọ́n kò ní leè dúró, nítorí ọ̀tẹ̀ tí ó gbérò sí i Àwọn tí ó jẹ nínú oúnjẹ ọba yóò gbìyànjú láti parun a ó gbá ogun rẹ̀ dànú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò ṣubú sí ogun Àwọn ọba méjèèjì, ọkàn wọn tẹ̀ sí búburú, wọn yóò jókòó lórí tábìlì kan, wọn yóò máa parọ́ sí ara wọn, ṣùgbọ́n kò ní yọrí sí nǹkan kan nítorí òpin yóò wá ní àsìkò tí a yàn Ọba àríwá yóò padà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ yóò lòdì sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì ṣiṣẹ́ lòdì sí i, yóò sì padà sí orílẹ̀-èdè oun fúnra rẹ̀ Ní àsìkò tí a yàn, yóò gbógun sí Gúṣù lẹ́ẹ̀ kan sí i, ṣùgbọ́n ní ìgbà yí àyọrísí yóò yàtọ̀ sí ti ìṣáájú Nítorí pé, ọkọ̀ ojú omi àwọn ilẹ̀ etídò ìwọ̀-oòrùn yóò ta kòó, ọkàn rẹ̀ yóò sì pámi Nígbà náà, ni yóò padà, yóò sì bínú sí májẹ̀mu mímọ́, yóò sì padà, yóò sì fi ojú rere hàn sí àwọn tí ó kọ májẹ̀mu mímọ́ náà Agbára ọmọ ogun rẹ̀ yóò dìde láti ba ohun mímọ́ ilé olódi tẹ́ḿpìlì jẹ́, yóò sì pa ẹbọ ojoojúmọ́ rẹ́ Nígbà náà ni wọn yóò gbé ìríra tí ó fa ìsọdahoro kalẹ̀ Pẹ̀lú ẹ̀tàn ni yóò bá àwọn tí ó ba májẹ̀mú jẹ́, ṣùgbọ́n, àwọn tí ó mọ Ọlọ́run wọn yóò jẹ́ alágbára Wọn yóò sì kọjú ìjà sí i Àwọn tí ó mòye yóò máa kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀, wọn yóò máa ṣubú nípa idà tàbí kí a jó wọn tàbí ìgbèkùn tàbí nípa ìkógún Nígbà tí wọ́n bá ṣubú, wọn yóò rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe aláìsòótọ́ yóò sì dara pọ̀ mọ́ wọn Lára àwọn tí ó mòye yóò kọsẹ̀, nítorí kí a baà tún wọn ṣe, wọ́n di mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ìgbà ìkẹyìn nítorí yóò sì wá ní àkókò tí a yàn Ọba yóò ṣe bí ó ti wù ú yóò sì gbé ara rẹ̀ ga, ju gbogbo òrìṣà lọ, yóò máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò-ṣe-é-gbọ́-létí sí Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run, a yóò sì máa yege títí àkókò ìbínú yóò fi parí, nítorí ohun tí a ti pinnu yóò ṣẹlẹ̀ Òun kò ní ka òrìṣà àwọn baba rẹ̀ sí tàbí èyí tí àwọn fẹ́, òun kò ní ka ìkankan sí, ṣùgbọ́n yóò gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo wọn lọ Ṣùgbọ́n dípò wọn, yóò bu ọlá fún òrìṣà àwọn ìlú olódi òrìṣà tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ni yóò bu ọlá fún pẹ̀lú wúrà àti fàdákà, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti ẹ̀bùn tí ó lówó lórí Yóò kọ lu àwọn ìlú olódi tí ó lágbára pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ òrìṣà àjèjì, yóò sì bu ọlá ńlá fún ẹni tí ó jẹ́wọ́ rẹ̀ Yóò mú wọn ṣe alákòóso lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí èrè Ní ìgbà ìkẹyìn, ọba Gúṣù yóò gbé ogun de sí i, ọba àríwá yóò sì jáde bí ìjì láti kọ lù ú pẹ̀lú u kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ ojú omi Yóò gbógun wọ orílẹ̀ èdè púpọ̀, yóò sì gbá wọn mọ́lẹ̀ bí ìkún omi Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì tún gbógun ti ilẹ̀ ológo náà pẹ̀lú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè yóò ṣubú, ṣùgbọ́n Édómù, Móábù àti àwọn olórí Ámónì yóò bọ́ lọ́wọ́ ọ rẹ̀ Yóò lo agbára rẹ̀ lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè Éjíbítì kì yóò là Yóò gba àkóso ìṣúra wúrà àti fàdákà àti gbogbo orò Éjíbítì, pẹ̀lú ti Líbíyà àti Núbíà nígbà tí ó mú wọn tẹríba Ṣùgbọ́n ìròyìn láti ìlà oòrùn àti láti ìwọ̀ oòrùn yóò mú ìdáríjì bá a, yóò sì fi ìbínú ńlá jáde lọ láti parun, àti láti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ run pátapáta Yóò sì pàgọ́ ọ rẹ̀ láàrin òkun kọjú sí àárin òkè mímọ́ ológo Síbẹ̀ yóò wá sí òpin rẹ̀, ẹnìkan kò ní ràn-án lọ́wọ́ Ìgbà Ìkẹyìn Ní àkókò náà, ni Máíkẹ́lì, ọmọ aládé ńlá, ẹni tí o n dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀, yóò dìde Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀ èdè títí di àkókò náà Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun Àwọn tí ó jẹ́ ọlọgbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé Ṣùgbọ́n ìwọ Dáníẹ́lì, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀ Nígbà náà, ni èmi Dáníẹ́lì, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá ọ̀hún etí i bèbè Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀ Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátapáta, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi Nígbà náà ni mo bèèrè pé, Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí Ó sì dáhùn pé, Má a lọ ní ọ̀nà rẹ, Dáníẹ́lì nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dìí di ìgbà ìkẹyìn Ọ̀pọ́lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láì lábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búrurú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró tì ọ́ àti tí ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì ọjọ́ Ṣùgbọ́n ìwọ, máa lọ ní ọ̀nà rẹ, títí di òpin Ìwọ yóò sinmi, àti ní òpin ọjọ́ ìwọ yóò dìde láti gba èrè rẹ Àlá Nebukadinéṣárì Ní ọdún kejì ìjọba Nebukadinéṣárì, ó lá àlá, èyí tí ó mú kí ọkàn an rẹ̀ dàrú, kò sì le è sùn Nígbà náà ni ọba yára pe àwọn onídán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn oṣó àti àwọn awòràwọ̀ àwọn tó ní ìmọ̀ àti àsírí i títúmọ̀ ìràwọ̀, ọba pè wọ́n kí wọn wá sọ àlá tí ó lá Nígbà tí wọ́n dé, tí wọ́n dúró níwájú ọba, ó sọ fún wọn pé, Mo ti lá àlá kan èyí tí ó mú kí ọkàn mi dàrú, mo sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ àlá náà Nígbà náà ni àwọn awòràwọ̀ dá ọba lóhùn ní èdè Árámáíkì pé, Kí ọba kí ó pẹ́! Sọ àlá yìí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ àwa yóò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ Ọba dá àwọn awòràwọ̀ lóhùn pé, Ohun náà ti kúrò lórí mi tí ẹ̀yin kò bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò gé e yín sí wẹ́wẹ́, ilé e yín yóò sì di ààtàn Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò fún un yín ní ẹ̀bùn, ọrẹ àti ọláńlá tí ó pọ̀ Nítorí náà, ẹ sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi Lẹ́ẹ̀kan sí i, Wọ́n tún dáhùn pé, jẹ́ kí ọba sọ àlá náà fún ìránṣẹ́ rẹ̀, àwa yóò sì túmọ̀ rẹ̀ Nígbà náà ni ọba sọ pé, Èmi mọ̀ dájú wí pé ẹ̀yin fẹ́ fi àkókò ṣòfò nítorí pé ẹ̀yin ti mọ̀ pé nǹkan ti lọ ní orí mi Tí ẹ̀yin kò bá lè sọ àlá mi, ìjìyà kan ṣoṣo ló wà fún un yín Ẹ̀yin ti gbèrò láti pa irọ́ àti láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ti ó lè ṣi ni lọ́nà fún mi, títí tí nǹkan yóò fi yí wọ́ Nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, èmi yóò sì mọ̀ pé ẹ lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi Àwọn awòràwọ̀ sì dá ọba lóhùn pé, Kò sí ènìyàn kan ní ayé tí ó lè sọ nǹkan tí ọba béèrè! Kò sí ọba náà bí ó ti wù kí ó tóbi àti kí ó lágbára tó, tí í béèrè irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tàbí awòràwọ̀ Nǹkan tí ọba béèrè yìí ṣòro púpọ̀ Kò sí ẹni tí ó lè fi han ọba à fi àwọn òrìṣà, tí wọn kì í gbé láàrin ènìyàn Èyí mú kí ọba bínú, ó sì kanra, nítorí náà ó pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn amòye Bábílónì run Nítorí náà àṣẹ yìí jáde lọ wí pé kí a pa àwọn amòye, wọ́n ránṣẹ́ pe Dáníẹ́lì pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti pa wọ́n Nígbà tí Áríókù, olórí àwọn olùṣọ́ ọba, jáde láti lọ pa àwọn amòye Bábílónì, Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ fún un pẹ̀lú ọgbọ́n àti òye Ó béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùṣọ́ ọba wí pé, Èéṣe tí àṣẹ ọba fi yá kánkán bẹ́ẹ̀ Áríókù sì ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Dáníẹ́lì Nígbà náà ni Dáníẹ́lì wọlé tọ ọba lọ, ó sì tọrọ kí ọba fún òun ní ààyè, òun yóò fi ìtumọ̀ àlá náà hàn fún ọba Nígbà náà ni Dáníẹ́lì padà lọ sí ilé e rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Hananíáyà, Míṣáẹ́lì àti Ásáríyà Ó sọ fún wọn pé kí wọn bèèrè fún àánú Ọlọ́run ọ̀run nípa àsírí náà, kí ọba má ba à pa àwọn run pẹ̀lú àwọn amòye Bábílónì Ní òru, àsírí náà hàn sí Dáníẹ́lì ní ojú ìran Nígbà náà ni Dáníẹ́lì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run Dáníẹ́lì wí pé Ọpẹ́ ni fún orúkọ Olúwa láé àti láéláé tirẹ̀ ni ọgbọ́n àti agbára Ó yí ìgbà àti àkókò padà ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àsírí hàn ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùn àti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára ó ti fi àwọn nǹkan tí a bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún mi nítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá Nígbà náà ni Dáníẹ́lì títọ́ Áríókù lọ, ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn amòye Bábílónì run, Dáníẹ́lì wí fún un pé, Má ṣe pa àwọn amòye Bábílónì run Mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, èmi yóò sí sọ ìtumọ̀ àlá rẹ̀ fún un Lẹ́ṣẹ̀kan náà, Áríókù yára mú Dáníẹ́lì lọ sí iwájú ọba, ó sọ fún ọba pé, Èmi ti rí ọkùnrin kan lára àwọn àjèjì tí ó wá láti Júdà, ẹni tí ó lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba Ọba béèrè lọ́wọ́ ọ Dáníẹ́lì ẹni tí a tún ń pè ní Beliteṣáṣárì pé, Ṣé ìwọ lè sọ ohun tí mo rí nínú àlá mi àti ìtumọ̀ ọ rẹ̀ fún mi Dáníẹ́lì dá ọba lóhùn pé, Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àsírí tí ọba béèrè fún ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àsírí hàn Ó ti fi han ọba Nebukadinéṣárì, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́ Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí Ọba, bí ìwọ ṣe ṣùn sórí ibùsùn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ ń ro àwọn ohun tó ń bọ̀, olùfihàn àsírí ń fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún ọ Ṣùgbn fún èmi, a fi àsírí yìí hàn mí, kì í ṣe pé mo ní ọgbọ́n tí ó pọ̀ ju ti alààyè kankan lọ, ṣùgbọ́n nítorí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá àti kí ó lè mọ ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ̀ Ìwọ ọba ń wo, ère ńlá kan tí ó dúró níwájú ù rẹ, ère náà ga, ó sì dára láti wò, ìrísí i rẹ̀ ba ni lẹ́rù jọjọ Orí ère náà jẹ́ kìkì wúrà, àyà rẹ̀ àti ọwọ́ ọ rẹ̀ jẹ́ fàdákà, inú àti ẹ̀gbẹ́ itan rẹ̀ jẹ́ idẹ, àwọn ẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ́ irin, àwọn àtẹ́lẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ́ apákan irin àti apákan amọ̀ Bí ó ṣe ń wò, òkúta kan wá, tí kò wá láti ọwọ́ ẹnìkankan Ó kọlu ère náà ní àtẹ́lẹṣẹ̀ irin àti amọ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́ẹ́wẹ́ Nígbà náà ni irin, amọ̀, idẹ, fàdákà àti wúrà fọ́ sí wẹ́wẹ́ lẹ́ṣẹ̀ kan náà, ó sì dàbí ìyàngbò tí a fẹ́ kúrò lórí ọkà ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn Afẹ́fẹ́ gbé gbogbo rẹ̀ lọ láì ṣẹ́ku ọ̀kan mọ́, òkúta tí ó fọ́ ère náà sì di òkè ńlá, ó sì gba gbogbo ayé Èyí ni àlá náà, nígbà yìí ni a ó wá sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba Ìwọ ọba jẹ́ ọba àwọn ọba Ọlọ́run ọ̀run ti fi ìjọba agbára, títóbi àti ògo fún ọ ní ọwọ́ rẹ ló fi gbogbo ènìyàn, àwọn ẹranko ìgbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run sí Ní ibi gbogbo tí wọ́n ń gbé, ó ti fi ọ́ ṣe olórí i wọn Ìwọ ni orí i wúrà náà Lẹ́yìn èyí ni ìjọba mìíràn yóò dìde, tí kò ní lágbára tó tìrẹ, lẹ́yìn in rẹ̀, ìjọba kẹta tí yóò dàbí idẹ, èyí tí yóò jọba lórí i gbogbo ayé Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìjọba kẹrin yóò wà, ìjọba náà yóò lágbára bí irin, gẹ́gẹ́ bí irin ti í fọ́, tó sì ń lọ gbogbo nǹkan àti bí irin ti í fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́, bẹ́ẹ̀ ni yóò fọ́ tí yóò sì lọ gbogbo àwọn tó kù Bí o ṣe rí i tí àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹṣẹ̀ jẹ́ apákan amọ̀ àti apákan irin, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yóò ṣe pín ṣùgbọ́n yóò sì ní agbára irin díẹ̀ nínú rẹ̀, bí ó ṣe rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀ Bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ ṣe jẹ́ apákan irin àti apákan amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóò lágbára lápákan tí kò sì ní lágbára lápákan Gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀, báyìí ni àwọn ènìyàn yóò ṣe dàpọ̀ mọ́ ara wọn ní ti ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n wọn kò ní wà ní ìṣọ̀kan, bí irin kò ṣe dàpọ̀ mọ́ amọ̀ Ní àsìkò àwọn ọba náà, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba èyí tí kò le è bàjẹ́ kalẹ̀, èyí tí a kò ní fi lé ẹlòmíràn lọ́wọ́ Yóò sì run gbogbo ìjọba, yóò sì mú wọn wá sí òpin, ṣùgbọ́n ìjọba yìí yóò dúró láéláé Gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i pé a gé òkúta láti ara òkè, láì ti ọwọ́ ẹnikẹ́ni wá, òkúta èyí tí ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fàdákà àti wúrà sí wẹ́wẹ́ Ọlọ́run tí ó tóbi ti fi han ọba, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú Òtítọ́ ni àlá náà, bẹ́ẹ̀ ni ìtúmọ̀ rẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé Nígbà náà, ni Nebukadinésárì ọba dojúbolẹ̀ níwájú u Dáníẹ́lì ó sì fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọn kí ó mu ọrẹ àti òórùn tùràrí fún Dáníẹ́lì Ọba wí fún Dáníẹ́lì pé, Dájúdájú Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn ọba gbogbo àti olùfihàn àwọn àsírí, nítorí tí ìwọ lè fi àsírí yìí hàn Nígbà náà ni ọba gbé Dáníẹ́lì ga, ó sì fún un ní ẹ̀bùn ńlá tí ó pọ̀ Ó sì fi ṣe olórí i gbogbo agbègbè ìjọba Bábílónì àti olórí gbogbo àwọn amòye Bábílónì Dáníẹ́lì béèrè lọ́wọ́ ọba, ó sì yan Sádírákì, Mésákì, àti Àbẹ́dinígò gẹ́gẹ́ bí alábojútó ìgbéríko Bábílónì ṣùgbọ́n Dáníẹ́lì fún ra rẹ̀ wà ní ààfin ọba Ère Góòlù Nebukadinéṣárì ọba gbẹ́ ère wúrà kan, èyí tí gíga rẹ̀ tó àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ tó ẹsẹ̀ mẹ́fà, ó sì gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà ní agbègbè ìjọba Bábílónì Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ aládé, àwọn olóyè, àwọn ìgbìmọ̀, àwọn baálẹ̀, àwọn balógun, àwọn onídàájọ́, àwọn olùtọ́jú ìṣúra àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba láti wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀ Nígbà náà ni àwọn ọmọ aládé, àwọn olóyè, àwọn onímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba, wọn péjọ láti ya ère tí Nebukadinésárì ọba gbé kalẹ̀ sí mímọ́, gbogbo wọn sì dúró síwájú u rẹ̀ Nígbà náà ni a kéde kígbe sókè wí pé, Ohun tí a paláṣẹ fún un yín láti ṣe nìyìí, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè àti èdè gbogbo Bí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò, kí ẹ wólẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ tí kò bá wólẹ̀, kí ó fi orí balẹ̀, kí a ju ẹni náà sínú iná ìléru Nítorí náà, bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè, àti èdè gbogbo wólẹ̀, wọ́n sì fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadinéṣárì gbé kalẹ̀ Ní àsìkò yìí ni àwọn awòràwọ̀ bọ́ síwájú, wọ́n sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ará a Júdà Wọ́n sọ fún ọba Nebukadinṣárì pé, Kí ọba kí ó pẹ́ Ìwọ ọba ti pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin gbọdọ̀ wólẹ̀ kí ó fi orí balẹ̀ fún ère wúrà àti ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó forí balẹ̀, a ó sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú iná ìléru Ṣùgbọ́n àwọn ará a Júdà kan wà, àwọn tí a yàn láti ṣe olórí agèégbè ìjọba Bábílónì Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, wọ́n ò ka ìwọ ọba sí Wọn kò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀ Nígbà náà ni Nebukadinéṣárì pàṣẹ ní ìrunú àti ìbínú pé kí a mú Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò wá, wọ́n sì mú wọn wá síwájú ọba Nebukadinéṣárì wí fún wọn wí pé, Ṣé òtítọ́ ni, Sádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò wí pé ẹ̀yin kò sin òrìṣà mi àti pé ẹ̀yin kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí èmi gbé kalẹ̀ Ní ìsinsìnyìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókun, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetan láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò dá ọba lóhùn wí pé, Nebukadinéṣárì, kì í ṣe fún wa láti gba ara wa sílẹ̀ níwájú u rẹ nítorí ọ̀rọ̀ yìí Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú un rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ dájú wí pé àwa kò ní sin òrìṣà rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀ Nígbà náà ni Nebukadinéṣárì bínú gidigidi sí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, ojú u rẹ̀ sì yípadà, ó sì pàṣẹ pé, kí wọn dá iná ìléru náà kí ó gbóná ní ìlọ́po méje ju èyí tí wọn ń dá tẹ́lẹ̀, ó sì pàṣẹ fún àwọn alágbára nínú ogun rẹ̀ pé, kí wọ́n de Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, kí wọn sì jù wọ́n sínú iná ìléru Nígbà náà ni a dè wọ́n pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn, ṣòkòtò, ìbòrí àti àwọn aṣọ mìíràn, a sì jù wọ́n sínú iná ìléru Nítorí bí àsẹ ọba ṣe le tó, tí iná ìléru náà sì gbóná, ọwọ́ iná pa àwọn ọmọ ogun tí wọ́n mú Sádírákì, Mésákì àti Àbẹ́dinígò lọ Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò ṣubú lulẹ̀ sínú iná ìléru náà pẹ̀lú bí a ṣe dè wọ́n Nígbà náà ni ó ya Nebukadinéṣárì ọba lẹ́nu, ó sì yára dìde dúró, ó bèèrè lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ pé, Ṣe bí àwọn mẹ́ta ni a gbé jù sínú iná Wọ́n wí pé, Òtítọ́ ni ọba Ó sì wí pé, Wò ó! Mo rí àwọn mẹ́rin tí a kò dè tí wọ́n ń rìn ká nínú iná, ẹnì kẹrin dàbí ọmọ Ọlọ́run Nígbà náà, ni Nebukadinésárì dé ẹnu ọ̀nà iná ìléru, ó sì kígbe pé, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀gá ògo, ẹ jáde, ẹ wá níbi! Nígbà náà ni Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò jáde láti inú iná Àwọn ọmọ aládé, ìjòyè, baálẹ̀, àwọn ìgbìmọ̀ ọba pé jọ sí ọ̀dọ̀ ọ wọn Wọ́n rí i wí pé iná kò ní agbára lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò jó wọn lára, bẹ́ẹ̀ ni irun orí i wọn kò jóná, àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn kò jóná, òórùn iná kò rùn ní ara wọn rárá Nígbà náà, ni Nebukadinésárì sọ wí pé, Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, ẹni tí ó rán ańgẹ́lì rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àsẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí forí balẹ̀ fún Ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn Nítorí náà, mo pa àṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, orílẹ̀ èdè tàbí èdè kan tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò kí a gé wọn sí wẹ́wẹ́ kí a sì sọ ilé e wọn di ààtàn nítorí kò sí Ọlọ́run mìíràn tí ó lè gba ènìyàn bí irú èyí Nígbà náà ni ọba gbé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò ga ní gbogbo agbégbé ìjọba Bábílónì Nebukadinéṣárì Lá Àlá Nípa Igi Nebukadinésárì ọba, Sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé Kí Àlàáfíà máa pọ̀ síi fún un yín Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀! Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ àmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo ti ṣe fún mi hàn Báwo ni àmì rẹ̀ ti tóbi tó, Báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó! Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni Èmi Nebukadinéṣárì wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà Mo lá àlá kan èyí tí ó bà mí lẹ́rù Nígbà tí mo wà lórí ibùṣùn mi, ìran tí ó jáde lọ́kàn mi dẹ́rù bà mí Nígbà náà, ni mo pàṣẹ pé kí a mú gbogbo àwọn amòye Bábílónì wá, kí wọn wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi Nígbà tí àwọn onídán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtúmọ̀ àlá náà fún mi Ní ìkẹyìn Dáníẹ́lì wá síwájú mi, mo sì sọ àlá náà fún Mo wí pé, Beliteṣásárì, olórí àwọn amòye, èmi mọ̀ wí pé ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ, kò sì sí àsírí kan tí ó ṣòro jù fún ọ Sọ àlá mi kí o sì túmọ̀ rẹ̀ fún mi Èyí ni ìran náà tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí igi kan láàrin ayé, igi náà ga gidigidi Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí i rẹ̀ sì ń kan ọ̀run a sì rí i títí dé òpin ayé Ewé e rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ká rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ Lórí ibùsùn mi, mo rí ìran náà, olùṣọ́ kan dúró ṣíwájú u mi, àní ẹni mímọ́ kan, ó ń bọ̀ wá láti ọ̀run ó kígbe sókè wí pé, Gé igi náà kí o sì gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò gbọn ewé ẹ rẹ̀ ká, kí o sì fọ́n èṣo rẹ̀ dànù Jẹ́ kí àwọn ẹranko tí ó wà lábẹ́ ẹ rẹ̀ sá àti àwọn ẹyẹ tí ó wà ní ẹ̀ka rẹ̀ kúrò Ṣùgbọ́n fi kùkùté àti gbòǹgbò o rẹ̀ tí a fi irin àti idẹ dè ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ àti sí orí i koríko igbó  Jẹ́ kí ìrì ọ̀run ṣẹ̀ sí i lára, kí ó sì jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ẹranko igbó láàrin ilẹ̀ ayé Jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ kí ó yí padà kúrò ní ti ènìyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀  Olùṣọ́ ni ó gbé ìpinnu náà jáde, àṣẹ sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́, kí gbogbo alààyè le mọ̀ wí pé, Ọ̀gá Ògò ni olórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹnikẹ́ni tí ó wù ú, òun sì ń gbé onírẹ̀lẹ̀ lórí i wọn Èyí ni àlá tí èmi Nebukadinéṣárì ọba lá Ní ìsinsìn yìí ìwọ Beliteṣáṣárì, sọ ohun tí ó túmọ̀ sí fún mi, nítorí kò sí amòye kan ní ìjọba mi, tí ó lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi Ṣùgbọ́n ìwọ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí tí ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà ní inú un rẹ Nígbà náà ni Dáníẹ́lì páyà gidigidi fún ìgbà díẹ̀, èrò inú un rẹ̀ sì bà á lẹ́rù Nígbà náà ni ọba wí pé, Beliteṣáṣárì, má ṣe jẹ́ kí àlá náà tàbí ìtumọ̀ rẹ̀ kí ó dẹ́rù bà ọ́ Beliteṣáṣárì sì dáhùn wí pé, Olúwa mi, kí àlá yìí jẹ́ ti àwọn ọ̀tá a rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn aṣòdì sí ọ Igi tí ìwọ rí, tí ó dàgbà, tí ó sì lágbára, tí orí i rẹ̀ sì ń kan ọ̀run, tí ó lẹ́wà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso, tí ó ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn, tí ó ṣe ààbò lórí ẹranko igbó àti èyí tí ẹ̀ka rẹ̀ pèsè àyè fún ẹyẹ ojú ọ̀run Èyí tí ewé e rẹ̀ lẹ́wà, tí èṣo rẹ̀ si pọ̀, nínú èyí tí oúnjẹ sì wà fún gbogbo ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí àwọn ẹranko ìgbó ń gbé, lórí ẹ̀ka èyí ti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní ibùgbé wọn Ìwọ ọba ni igi náà, ìwọ ti dàgbà, o sì lágbára, títóbi i rẹ ga ó sì kan ọ̀run, ìjọba rẹ sì gbilẹ̀ títí dé òpin ayé Ìwọ ọba, rí ìránṣẹ́ ẹni mímọ́ kan, tí ó ń bọ̀ láti ọ̀run ó sì sọ pé, Gé igi náà kí o sì run ún, ṣùgbọ́n fi kùkùté rẹ tí a dè pẹ̀lú irin àti idẹ sílẹ̀ nínú koríko igbó, nígbà tí gbòǹgbò rẹ̀ sì wà nínú ilẹ̀ kí o sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run ṣẹ̀ sórí i rẹ̀, jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà láàrin ẹranko búburú títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀ Èyí ni ìtúmọ̀ àlá rẹ ọba àti àṣẹ tí Ọ̀gá Ògo mú wá sórí ọba olúwa mi A ó lé ọ jáde kúrò láàrin ènìyàn, ìwọ yóò sì máa gbé láàrin ẹranko búburú ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run yóò sì sẹ̀ sára rẹ Ìgbà méje yóò sì kọjá lórí ì rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé Ọ̀gá Ògo ń jọba lórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú Bí wọ́n ṣe pàṣẹ pé kí wọn fi kùkùté àti gbòǹgbò igi náà sílẹ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé a ó dá ìjọba rẹ padà fún ọ lẹ́yìn ìgbà tí o bá ti mọ̀ wí pé, Ọ̀run jọba Nítorí náà ọba, jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọ, kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀ kí o sì ṣe rere, àti ìwà búburú rẹ nípa ṣíṣe àánú fún àwọn talákà Ó lè jẹ́ pé nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe rere Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinéṣárì ọba Lẹ́yìn oṣù kejìla, bí ọba ṣe ń rìn káàkiri lórí òrùlé ààfin ìjọba Bábílónì, Ó sọ pé, Èyí ha kọ́ ni Bábílónì ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi Bí ọba ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ohùn kan wá láti ọ̀run Ìwọ Nebukadinéṣárì ọba, ìwọ ni a ti pàṣẹ nípa rẹ̀, a ti gba ìjọba à rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ rẹ A ó lé ọ kúrò láàrin àwọn ènìyàn, ìwọ yóò sì lọ máa gbé àárin àwọn ẹranko igbó ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìgbà méje yóò kọjá lórí i rẹ títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé, Ọ̀gá Ògo jọba lórí ìjọba ènìyàn àti pé ó ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú Lẹ́ṣẹ̀kẹṣẹ̀ ni ohun tí a sọ nípa Nebukadinéṣárì ṣẹlẹ̀ sí i A lé e kúrò láàrin ènìyàn, ó sì ń jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run sì ń ṣẹ̀ sí ara rẹ̀, títí irun orí i rẹ̀ fi gùn bí i ti ìyẹ́ ẹyẹ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dàbí i ti ẹyẹ Ní òpin ìgbà náà, Èmi, Nebukadinéṣárì gbé ojú ù mi sókè sí ọ̀run, iyè mi sì sọjí Mo fi ọpẹ́ fún Ọ̀ga Ògo mo fi ọlá àti ògo fún ẹni tí ó wà láéláé Ìjọba rẹ̀ ìjọba títí ayé ni ìjọba rẹ̀ wà láti ìran dé ìran Gbogbo àwọn ènìyàn ayé ni a kà sí asán Ó ń ṣe bí ó ti wù ú, pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run, àti gbogbo àwọn ènìyàn ayé tí kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè dí i lọ́wọ́ tàbí sọ fún un wí pé Kí ni ìwọ ń ṣe Ní àkókò kan náà, iyè mi padà, ọlá àti ògo dídán mi padà tọ̀ mí wá fún ògo ìjọba mi Àwọn ìgbìmọ̀ àti àwọn ọlọ́lá mi, wá mi rí, wọ́n sì dá mi padà sórí ìjọba mi, mo sì di alágbára ju ti ìṣáájú lọ Báyìí, èmi, Nebukadinéṣárì fi ọpẹ́, mo sì gbé Ọlọ́run ga, mo sì fi ògo fún ọba ọ̀run, nítorí pé gbogbo nǹkan tí ó ṣe ló dára, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì tọ́ Gbogbo àwọn tó sì ń rìn ní ìgbéraga ni ó le rẹ̀ sílẹ̀ Àkọsílẹ̀ Ara Ògiri Beliṣáṣárì, ọba ṣe àsè ńlá fún ẹgbẹ̀rún kan nínú àwọn ọlọ́lá a rẹ̀, ó sì mu wáìnì pẹ̀lú u wọn Bí Beliṣáṣárì ṣe ń mu wáìnì, ó pàṣẹ pé kí wọn kó kọ́ọ̀bù wúrà àti ti fàdákà wá, èyí tí Nebukadinéṣárì bàbá rẹ̀ kó wá láti inú tẹ́ḿpìlì ní Jérúsálẹ́mù, kí ọba àti àwọn ọlọ́lá a rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀ kí ó ba à le fi mu wáìnì Wọ́n sì kó kọ́ọ̀bù wúrà àti fàdákà àti fàdákà èyí tí wọ́n kó jáde láti inú tẹ́ḿpìlì, ilé Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù, ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀, sì fi mu wáìnì Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń yin òrìṣà wúrà àti fàdákà, ti idẹ, irin, igi àti òkúta Lójijì, ìka ọwọ́ ènìyàn jáde wá, ó sì ń kọ̀wé sára ẹfun ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ibi tí àtùpà ń dúró ní ààfin ọba Ọba ń wo ọwọ́ náà bí ó ṣe ń kọ ọ́ Ojú ọba sì yí padà, ẹ̀rù sì bàá, tó bẹ́ẹ̀ tí orúnkún ẹṣẹ̀ rẹ̀ méjèèjì rẹ̀ fi ń gbá ara wọn Ọba kígbe pé, kí wọn pe àwọn awòràwọ̀, àwọn onídán, àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, ọba sì sọ fún àwọn amòye Bábílónì pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka àkọsílẹ̀ yìí kí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹni náà ni a ó fi aṣọ eléṣèé àlùkò wọ̀ àti ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọrùn un rẹ̀, òun ni yóò sì ṣe olórí kẹta ní ìjọba à mi Nígbà náà ni gbogbo àwọn amòye ọba wọ ilé, ṣùgbọ́n, wọn kò le ka àkọsílẹ̀ náà tàbí sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba Nígbà náà ni Beliṣáṣárì ọba bínú gidigidi, ojú u rẹ̀ sì túbọ̀ dàrú síi Ẹ̀rù sì ba àwọn ìjòyè rẹ̀ Nígbà tí ayaba gbọ́ ohùn ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó wá ilé àsè wá Ó wí pé, Kí ọba kí ó pẹ́! Má ṣe jẹ́ kí inú un rẹ bàjẹ́, má sì ṣe jẹ́ kí ojú u rẹ fàro Ọkùnrin kan wà ní ìjọba à rẹ, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run, mímọ́ ń gbé inú un rẹ̀ Ní ìgbà ayé e bàbá à rẹ, òun ni ó ní ojú inú, òye àti ìmọ̀ bí i ti Ọlọ́run òun ni ọba Nebukadinéṣárì, bàbá rẹ̀ fi jẹ olórí àwọn onídán, awòràwọ̀, apògèdè àti aláfọ̀ṣẹ Ọkùnrin náà ni Dáníẹ́lì ẹni tí ọba ń pè ní Beliteṣáṣárì, ó ní ẹ̀mí tí ó tayọ, ìmọ̀ àti òye, àti agbára láti túmọ̀ àlá, ó máa ń ṣe àlàyé àlá àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá dojúrú, ránsẹ́ pè é, yóò sì sọ nǹkan tí àkọsílẹ̀ ìwé náà túmọ̀ sí Nigbà náà ni a mú Dáníẹ́lì wá ṣíwájú ọba, ọba sì sọ fún-un wí pé, Ṣé ìwọ ni Dáníẹ́lì, ọ̀kan lára àwọn tí bàbá mi mú ní ìgbékùn láti Júdà! Mo ti gbọ́ wí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú un rẹ àti wí pé ìwọ ní ojú inú, òye, àti ọgbọ́n tí ó tayọ A ti mú àwọn amòye àti àwọn awòràwọ̀ wá sí iwájú mí kí wọn ba à le è wá ka àkọsílẹ̀ yìí kí wọn sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ ohun tí ó jẹ́ Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ wí pé, ìwọ lè sọ ìtumọ̀, àti wí pé o lè yanjú àwọn ìṣòro tó lágbára Tí o bá lè ka àkọsílẹ̀ ìwé yìí kí o sì sọ ìtúmọ̀ rẹ̀, a ó fi aṣọ eléṣèé àlùkò wọ̀ ọ́ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọ lọ́rùn, a ó sì fi ọ́ ṣe olórí kẹta ní ìjọba mi Nígbà náà ni Dáníẹ́lì dá ọba lóhùn wí pé, Fi ẹ̀bùn rẹ pamọ́ fún ara rẹ, tàbí kí o fún ẹlòmíràn Síbẹ̀ èmi yóò ka àkọsílẹ̀ náà fún ọba, èmi yóò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ Ìwọ ọba, Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo fún Nebukadinésárì baba rẹ ní ìjọba, títóbi ògo àti ọlá Nítorí ipò ńlá tí a fi fún un, gbogbo ènìyàn orílẹ̀ èdè àti èdè gbogbo fi ń páyà tí wọ́n sì ń bẹ̀rù rẹ̀ Ó ń pa àwọn tí ó bá wù ú, ó sì ń dá àwọn tí ó bá wù ú sí, ó ń gbé àwọn tí ó bá wù ú ga, ó sì ń rẹ àwọn tí ó bá wù ú sílẹ̀ Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn rẹ̀ ga, tí ó sì le koko Ó bẹ̀rẹ̀ sí i hùwà ìgbéraga, a mú u kúrò lórí ìtẹ́ ọba rẹ̀, a sì gba ògo rẹ̀ kúrò A lé e kúrò láàrin ènìyàn, a sì fún un ní ọkàn ẹranko ó sì ń gbé pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì ń jẹ koríko bí i ti màlúù ìrì ọ̀run sì ṣẹ̀ sí ara rẹ̀, títí tó fi mọ̀ pé, Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo ń jọba lórí ìjọba ọmọ ènìyàn, òun sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú Ṣùgbọ́n ìwọ ọmọ rẹ̀, Beliṣáṣárì, ìwọ kò rẹ ara à rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ mọ nǹkan wọ̀nyí Dípò èyí, ìwọ gbé ara à rẹ ga sí Olúwa ọ̀run, a mú kọ́ọ̀bù inú tẹ́ḿpìlì rẹ̀ wá sí iwájú ù rẹ, ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlè rẹ fi ń mu wáìnì Ìwọ ń yin àwọn òrìṣà fàdákà àti wúrà, idẹ, irin, igi àti ti òkúta, èyí tí kò lè ríran, tí kò le è gbọ́ran tàbí ní òye nǹkan kan Ṣùgbọ́n ìwọ kò bu ọlá fún Ọlọ́run ẹni tó ni ẹ̀mí ì rẹ lọ́wọ́, tí ó sì mọ gbogbo ọ̀nà rẹ Nítorí náà, ó rán ọwọ́ tí ó kọ àkọlé yìí Èyí ni àkọlé náà tí a kọ MENE, MENE, TÉKÉLÌ, PÉRÉSÍNÌ Èyí ni nǹkan tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí Mene Ọlọ́run ti sírò ọjọ́ ìjọba rẹ Ó sì ti mú u wá sí òpin Tékélì A ti gbé ọ lórí òṣùwọ̀n, ìwọ kò sì tó ìwọ̀n Pérésínì A ti pín ìjọba rẹ a sì ti fi fún àwọn Médíà àti àwọn Páṣíà Nígbà náà ni Beliṣáṣárì pàṣẹ pé kí a wọ Dáníẹ́lì ní aṣọ eléṣèé àlùkò, kí a sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, a sì kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí kẹta ní ìjọba rẹ̀ Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni a pa Beliṣáṣárì, ọba Bábílónì Dáríúsì ará Médíánì sì gba ìjọba nígbà tí ó di ọmọ ọdún méjìlélọ́gọ́ta Dáníẹ́lì Nínú Ihò Kìnìún Ó dára lójú Dáríúsì láti yan ọgọ́fà àwọn baálẹ̀ sórí ìjọba, pẹ̀lú alákòóso mẹ́ta, Dáníẹ́lì sì jẹ́ ọ̀kan nínú un wọn, kí àwọn baálẹ̀ lè wá máa jẹ́ ààbọ̀ fún wọn, kí ọba má ba à ní ìpalára Dáníẹ́lì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láàrin àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ nítorí ẹ̀mí tí ó tayọ wà lára rẹ̀ dé bi pé ọba sì ń gbérò láti fi ṣe olórí i gbogbo ìjọba Nítorí èyí, gbogbo àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ ń gbérò láti wá ẹ̀ṣẹ̀ kà sí Dáníẹ́lì lọ́rùn nínú ètò ìṣèjọba rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan kà sí i lọ́rùn, wọn kò rí ìwà ìbàjẹ́ kankan tí ó ṣe, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ kò sì ní ìwà ìjáfara Nígbẹ̀yìn ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí sọ wí pé, Àwa kò ní rí ìdí kankan láti kà ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn, àfi èyí tí ó bá ní í ṣe pẹ̀lú òfin Ọlọ́run rẹ̀ Nígbà náà ni àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọ́n wí pé Ìwọ Dáríúsì ọba, kí o pẹ́! Àwọn alákòóso ọba, ìjòyè, baálẹ̀, olùdámọ̀ràn, àti àwọn olórí gbìmọ̀ pọ̀ wí pé kí ọba kéde òfin kan pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, yàtọ̀ fún ìwọ ọba, a ó ju ẹni náà sí inú ihò kìnnìún Nísinsin yìí, ìwọ ọba, gbé òfin yìí jáde, kí o sì kọ ọ́ sínú ìwé kí a má ba à yí i padà ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn Médíánì àti Páṣíà, èyí tí kò ní le è parẹ́ Nígbà náà, ni Dáríúsì ọba fi ọwọ́ sí ìwé àṣẹ náà Lóòótọ́ Dáníẹ́lì mọ̀ pé a ti fi ọwọ́ sí ìwé òfin náà, síbẹ̀ ó wọ ilé e rẹ̀ lọ, nínú yàrá òkè, ó sí fèrèsé èyí tí ó kọjú sí Jérúsálẹ́mù sílẹ̀ Ó kúnlẹ̀ lórí orúnkún un rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta lójoojúmọ́, ó gbàdúrà, ó fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ tẹ́lẹ̀ Nígbà náà ni, àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí Dáníẹ́lì tí ó ń gba àdúrà, ó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ Ọlọ́run Wọ́n lọ sí iwájú ọba, wọ́n sì rán ọba létí nípa òfin tí ó ṣe pé, Ìwọ kò ha fi ọwọ́ sí òfin wí pé ní ìwọ̀n ọgbọ̀n ọjọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn, láì bá ṣe ìwọ ọba, a ó gbé e jù sínú ihò kìnnìún Ọba sì dáhùn pé, Àṣẹ náà dúró ṣíbẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn ará Médíánì àti Páṣíà, èyí tí a kò le è parẹ́ Nígbà náà, ni wọ́n sọ fún ọba pé, Dáníẹ́lì, ọ̀kan lára ìgbékùn Júdà, kò ka ìwọ ọba sí, tàbí àṣẹ ẹ̀ rẹ tí o fi ọwọ́ sí Òun sì tún ń gba àdúrà ní ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́ Nígbà tí ọba gbọ́ èyí, inú un rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi ó pinnu láti kó Dáníẹ́lì yọ, títí òòrùn fi rọ̀, ó sa gbogbo ipá a rẹ̀ láti gba Dáníẹ́lì sílẹ̀ Nígbà náà, ni àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí kó ara wọn jọ wá sí ọ̀dọ̀ ọba, wọ́n sì wí fún un pé, Ìwọ ọba rántí pé, ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn Médíà àti Páṣíà kò sí àṣẹ tàbí ìkéde tí ọba ṣe tí a le è yí i padà Nígbà náà, ni ọba pàṣẹ, wọ́n sì mú Dáníẹ́lì, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò kìnnìún Ọba sì sọ fún Dáníẹ́lì pé, Kí Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn nígbà gbogbo kí ó gbà ọ́! A sì gbé òkúta kan wá, wọ́n sì fi dí ẹnu ihò náà, ọba sì dí i pa pẹ̀lú òrùka èdìdì rẹ̀ àti pẹ̀lú òrùka àwọn ọlọ́lá rẹ̀, nítorí kí a má ṣe yí ohunkóhun padà nítorí i Dáníẹ́lì Nígbà náà ni ọba padà sí ààfin rẹ̀, ó sì lo gbogbo òru náà láì jẹun, kò sì gbọ orin kankan, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le è ṣùn ní òru ọjọ́ náà Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, ni ọba dìde ó sì sáré lọ sí ibi ihò kìnnìún náà Nígbà tí ó sún mọ́ ibi ihò náà ní ibi tí Dáníẹ́lì wà, ó pe Dáníẹ́lì pẹ̀lú ìtara pé, Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, ṣé Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn tọ̀sán tòru, lè gbà ọ́ lọ́wọ́ ọ kìnnìún bí Dáníẹ́lì sì dáhùn wí pé, Ọba kí ẹ pẹ́! Ọlọ́run mi rán ańgẹ́lì i rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún lẹ́nu Wọn kò le è pamí lára, nítorí a rí mi gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀ ní iwájú rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò hu ìwà ìbàjẹ́ kan níwájú rẹ ìwọ ọba Inú ọba dùn gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a mú Dáníẹ́lì jáde wá láti inú ihò Nígbà tí a mú Dáníẹ́lì jáde nínú ihò, kò sí ojú ọgbẹ́ kan ní ara rẹ̀, nítorí tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run rẹ̀ Ọba pàṣẹ pé, kí a mú àwọn alátakò Dáníẹ́lì wá, kí a jù wọ́n sí inú ihò kìnnìún, pẹ̀lú ìyàwó àti àwọn ọmọ wọn Kí wọn tó dé ìsàlẹ̀ ihò, kìnnìún lágbára lórí i wọn, wọ́n sì fọ́ gbogbo egungun wọn Nígbà náà, ni Dáríúsì ọba kọ̀wé sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè àti gbogbo jákèjádò ilẹ̀ náà Kí ire yín máa pọ̀ sí i! Mo gbé àsẹ kan jáde wí pé ní gbogbo agbègbè ìjọba mi, gbogbo ènìyàn gbọdọ̀ bẹ̀rù, kí wọn kí ó sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Dáníẹ́lì Nítorí òun ni Ọlọ́run alààyè Ó sì wà títí ayé Ìjọba rẹ̀ kò le è parun ìjọba rẹ̀ kò ní ìpẹ̀kun Ó ń yọ ni, ó sì ń gba ni là ó ń ṣe iṣẹ́ àmì àti ìyanu ní ọ̀run àti ní ayé Òun ló gba Dáníẹ́lì là kúrò lọ́wọ́ agbára kìnnìún Dáníẹ́lì sì ṣe rere ní àkókò ìjọba Dáríúsì àti àkókò ìjọba Sáírúsì ti Páṣíà Dáníẹ́lì Lá Àlá Ẹranko Mẹ́rin Ní ọdún àkọ́kọ́ Beliṣáṣárì ọba Bábílónì, Dáníẹ́lì lá àlá kan, ìran náà sì wá sí ọkàn an rẹ̀ bí ó ṣe ṣùn sórí ibùṣùn un rẹ̀, ó sì kọ àlá náà sílẹ̀ Dáníẹ́lì sọ pé, Nínú ìran mi lóru mo wò ó, mo sì rí afẹ́fẹ́ ọ̀run mẹ́rin tí ó ń ru omi òkun ńlá sókè Ẹranko ńlá mẹ́rin tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, jáde láti inú òkun náà Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́-apá a idì mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́-apá rẹ̀ naa tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un Mo sì tún rí ẹranko kejì, ó rí bí irú ẹranko ńlá kan tí ó ń gbé ilẹ̀ òtútù bíárì Ó gbé ara sókè ní apá kan, ó sì ní egungun ìhà mẹ́ta láàrin ẹ̀yìn in rẹ̀, wọ́n sì sọ fún un pé, Dìde kí o sì jẹ ẹran tó pọ̀! Lẹ́yìn ìgbà náà, mo tún rí ẹranko kẹta ó rí bí àmọ̀tẹ́kùn Ẹranko náà ní ìyẹ́ bí i ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn, ó sì ní orí mẹ́rin, a sì fún un ní agbára láti ṣe ìjọba Lẹ́yìn èyí, nínú ìran mi lóru mo tún rí ẹranko kẹrin, ó dẹ́rù ba ni, ó dáyà fo ni, ó sì lágbára gidigidi Ó ní eyín irin títóbi ó ń rùn, ó sì ń pa ohun alààyè tí ó ṣẹ́ kù jẹ, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tó kù mọ́lẹ̀ Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko ti ìṣáájú, ó sì ní ìwo mẹ́wàá Bí mo ṣe ń ronú nípa ìwo náà, nígbà náà ni mo rí ìwo mìíràn, tí ó kéré tí ó jáde wá ní àárin wọn mẹ́ta lára àwọn ìwo ti àkọ́kọ́ sì fà tu níwájú u rẹ̀ Ìwo yìí ní ojú bí i ojú ènìyàn àti ẹnu tí ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga Bí mo ṣe ń wò, a gbé ìtẹ́ ọba sí ìkàlẹ̀ ẹni ìgbàanì orí ìtẹ́ rẹ̀ Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú Irun orí i rẹ̀ funfun bí òwú Ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná Odò iná ń ṣàn ó ń jáde ní iwájú u rẹ̀ Àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́ná ẹgbẹ̀rún ń forí balẹ̀ fún un Ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì dúró níwájú u rẹ̀ Àwọn onídàájọ́ jókòó a sì sí àwọn ìwé sílẹ̀ Nígbà náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní wò, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga tí ìwo náà ń sọ, mo wò títí a fi pa ẹranko náà, a sì pa á run, a sì jù ú sínú iná tí ń jó A sì gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ẹranko yóòkù, ṣùgbọ́n a fún wọn láàyè láti wà fún ìgbà díẹ̀ Nínú ìran mi ní òru mo wò, mo rí ẹnìkan tí ó dúró sí iwájú u mi, ó rí bí ọmọ ènìyàn, ó ń bọ̀ wá nínú àwọ̀ọsánmọ̀ ọ̀run, ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ ẹni ìgbàanì, a sì mú u wá sí iwájú rẹ̀ A sì fi ìjọba, ògo àti agbára ilẹ̀ ọba fún un gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè àti èdè gbogbo wọn wólẹ̀ fún un Ìjọba rẹ̀, ìjọba ayérayé ni, èyí tí kò le è kọjá, ìjọba rẹ̀ kò sì le è díbàjẹ́ láéláé Ọkàn èmi Dáníẹ́lì, dàrú, ìran tí ó wá sọ́kàn mi dẹ́rù bà mí Mo lọ bá ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀, mo sì bi í léèrè òtítọ́ ìtúmọ̀ nǹkan wọ̀nyí Ó sọ fún mi, ó sì túmọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún mi Àwọn ẹranko ńlá mẹ́rin yìí, ni ìjọba mẹ́rin tí yóò dìde ní ayé Ṣùgbọ́n, ẹni mímọ́ ti ọ̀gá ògo ni yóò gba ìjọba náà, yóò sì jogún un rẹ títí láé àti títí láéláé Nígbà náà, ni mo fẹ́ mọ ìtúmọ̀ òtítọ̀ ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí àwọn yóòkù, èyí tí ó dẹ́rù ba ni gidigidi, tí ó ní eyín irin àti èékánná idẹ, ẹranko tí ó ń run tí ó sì ń pajẹ, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tó kù mọ́lẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni mo sì fẹ́ mọ̀ nípa ìwo mẹ́wàá orí i rẹ̀ àti nípa ìwo yóòkù tí ó jáde, nínú èyí tí mẹ́ta lára wọn ṣubú, ìwo tí ó ní ojú, tí ẹnu rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìgbératga Bí mo ṣe ń wò, ìwo yìí ń bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, ó sì borí i wọn, títí ẹni ìgbàanì fi dé, ó sì ṣe ìdájọ́ ìdáláre fún àwọn ẹni mímọ́ ọ̀gá ògo, àsìkò náà sì dé nígbà tí àwọn ẹni mímọ́ náà jogun ìjọba Ó ṣe àlàyé yìí fún mi pé Ẹranko kẹrin ni ìjọba kẹrin tí yóò wà ní ayé Yóò yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ìjọba yóòkù yóò sì pa gbogbo ayé run, yóò tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀, yóò sì fọ́ ọ́ sí wẹ́wẹ́ Ìwo mẹ́wàá ni ọba mẹ́wàá tí yóò wá láti inú ìjọba yìí Lẹ́yìn tí wọn ní ọba mìíràn yóò díde, ti yóò yàtọ̀ sí tí àwọn ti ìṣáájú, yóò sì borí ọba mẹ́ta Yóò sọ̀rọ̀ odi sí ọ̀gá ògo, yóò sì pọ́n ẹni mímọ́ lójú, yóò sì gbèrò láti yí ìgbà àti òfin padà A ó fi àwọn ẹni mímọ́ lé e lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀, ní ọdún méjì àti ààbọ̀  Ṣùgbọ́n àwọn onídàájọ́ yóò jókòó, nígbà náà ni a ó gba agbára rẹ̀, a ó sì pa á rùn pátapáta títí ayé Nígbà náà, ni a ó gba ìjọba, agbára àti títóbi ìjọba rẹ̀ ní abẹ́ gbogbo ọ̀run, a ó sì fi fún àwọn ẹni mímọ́, àwọn ènìyàn ọ̀gá ògo Ìjọba rẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba títí ayé, gbogbo aláṣẹ ni yóò máa ṣe ìgbọràn sí i, wọn yóò sì máa sìn ín Báyìí ni àlá náà ṣe parí, ọkàn èmi Dáníẹ́lì sì dàrú gidigidi, nítorí èrò ọkàn mi yìí, ojú mi sì yípadà ṣùgbọ́n mo pa ọ̀ràn náà mọ́ ní ọkàn mi Dáníẹ́lì Rí Ìran Àgbò Kan Àti Òbúkọ Kan Nígbà tí ó di ọdún kẹta ìjọba Beliṣáṣárì ọba, èmi Dáníẹ́lì rí ìran kan èyí tí mo ti rí tẹ́lẹ̀ Nínú ìran náà, mo rí ara mi nínú ilé ìṣọ́ ní Súsáni ní agbègbè ìjọba Élámù nínú ìran náà mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Úláì Mo wo òkè mo sì rí àgbò kan tí ó ní ìwo méjì níwájú ù mi, ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Úláì, àwọn ìwo méjèèje sì gùn Ṣùgbọ́n ọ̀kan gùn ju èkejì lọ, èyí tí ó gùn jù ni ó yọ jáde kẹ́yìn Mo rí àgbò náà ó ń kàn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, sí àríwá, àti sí gúsù, kò sí ẹranko kankan tí ó leè dojú kọọ́, kò sí ẹnìkan tí ó leè yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀, ó ń ṣe bí ó ti wù ú, ó sì di alágbára Bí mo ṣe ń ronú nípa èyí, lójijì ni òbúkọ kan tí ó ní ìwo láàrin ojú u rẹ̀ méjèèjì jáde láti ìhà ìwọ̀ oòrùn, ó la gbogbo ayé kọjá láì fi ara kan ilẹ̀ Ó tọ àgbò tí ó ni ìwo méjì náà wá, èyí tí mo rí tó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Úláì, ó sì dojú kọ ọ́ pẹ̀lú ìrunú tí ó lágbára Mo ríi tí ó fi ìtara kọlu àgbò náà, ó lu àgbò náà bolẹ̀, ó sì ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì Àgbò náà kò sì ní agbára láti dojú kọ ọ́, Òbúkọ náà kàn-án mọ́lẹ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀, kò sì sí ẹni tí ó lè gba àgbò náà là kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀ Òbúkọ náà sì di alágbára púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé góńgó, agbára rẹ̀ ru sókè, ìwo ńlá a rẹ̀ sì ṣẹ́ dànù, ní ipò o rẹ̀, ìwo mẹ́rin mìíràn hù, ó sì yọrí sí ìhà igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run Lára ọ̀kan nínú un wọn, ìwo mìíràn yọ jáde, ó kékeré, ṣùgbọ́n ó dàgbà nínú agbára sí ìhà gúsù, àti sí ìhà ìlà oòrun àti sí ilẹ̀ dídára Ó sì dàgbà títí ó fi kan ẹgbẹ́ ogun ọ̀run, ó sì jù lára àwọn ẹgbẹ́ ogun ọ̀run sí ayé ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, ó sì gbé ara rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí ọmọ aládé ẹgbẹ́ ogun ọ̀run ó sì mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò lọ́dọ̀ ọ rẹ̀, ó sì gba àyè ibi mímọ́ rẹ̀ A fún-un ní ẹgbẹ́ ogun ọ̀run àti ẹbọ ojojúmọ́ nítorí ìwà ọlọ̀tẹ̀ ẹ rẹ̀ ó sọ òtítọ́ nù nínú gbogbo ohun tó ṣe Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ ń sọ̀rọ̀, àti ẹni mímọ́ mìíràn sọ̀rọ̀ fún-un pé, Yóò ti pẹ́ tó tí ìran yìí yóò fi wá sí ìmúsẹ-ìran nípa ẹbọ ojojúmọ́, ìṣọ̀tẹ̀ tí ó ń sọ dahoro, àti mímú kí ibi mímọ́ àti ẹgbẹ́ ogun ọ̀run di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ Ó sọ fún mi pé, Yóò gbà tó ẹgbọ̀kànlá lé lọ́gọ́rùn-ún alẹ́ àti òwúrọ̀ lẹ́yìn náà ni a ó tún ibi mímọ́ yà sí mímọ́ Nígbà tí èmi Dáníẹ́lì, ń wo ìran náà, mo sì ń fẹ́ kí ó yé mi, ẹnìkan tí ó sì dúró níwájú ù mi Mo gbọ́ ohùn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ Úláì, tí ó ń pè pẹ́ Gébúrẹ́lì, sọ ìtumọ̀ ìran náà fún ọkùnrin yìí Bí ó ṣe súnmọ́ ibi tí mo dúró sí, ẹ̀rù bàmí, mo sì dọ̀bálẹ̀ Ó ń sọ fún mi pé, Ọmọ ènìyàn, jẹ́ kí ó yé ọ pé ìran náà ń sọ nípa ìgbà ìkẹyìn ni Bí ó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo ti sùn lọ fọnfọn, bí mo ṣe da ojú bolẹ̀ Nígbà náà ni ó fi ọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi Ó sọ wí pé Èmi yóò sọ ohun tí yóò sẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ní ìgbà ìbínú, nítorí ìran náà jẹ mọ́ àkókò ohun tí a yàn nígbà ìkẹyìn Àgbò oníwo méjì tí o rí, òun ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba Médíánì àti Páṣíà Òbúkọ onírun náà ni ọba Gíríkì, ìwo ńlá ti ó wà láàrin ojú u rẹ̀ ni ọba àkọ́kọ́ Ìwo mẹ́rin ti ó dípo ọ̀kan tí ó kán dúró, èyí dúró gẹ́gẹ́ bí ìjọba mẹ́rin tí ó dìde láti orílẹ̀ èdè e rẹ̀ ṣùgbọ́n wọn kò ní ní irú agbára kan náà Ní ìgbà ìkẹyìn ìjọba wọn, nígbà tí ìwà búburú àwọn ọlọ̀tẹ̀ bá burú gidigidi ọba tí ojú u rẹ̀ le koko, balógun rìkísí yóò dìde Yóò di alágbára, ṣùgbọn tí kì í ṣe nípa agbára rẹ̀ Yóò sì máa ṣe ìparun tí yóò ya ni lẹ́nu, yóò sì máa ṣe àṣeyọri nínú ohun gbogbo tó ń ṣe Yóò sì run àwọn alágbára àti àwọn ènìyàn mímọ́ Nípa àrékérekè rẹ̀, yóò mú kí ẹ̀tàn gbèrú, yóò gbé ara rẹ̀ ga nínú ọkàn rẹ̀, nígbà tí wọ́n rò wí pé àlàáfíà dé, yóò sì pa àwọn ènìyàn run, nígbà tí wọn kò rò tẹ́lẹ̀, yóò sì lòdì sí olórí àwọn ọmọ aládé, ṣíbẹ̀, a ó paárun ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa agbára ènìyàn Ìran alẹ́ àti ti òwúrọ̀, tí a fi hàn ọ́ jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n pa ìran náà mọ́, nítorí pé, ó jẹ mọ́ ti ọjọ́ iwájú Èmi Dáníẹ́lì sì ṣe àárẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan Nígbà náà, mo dìde, mo sì ń bá isẹ́ ọba lọ Ìran náà sì bàmí lẹ́rù, kò sì yé mi Àdúrà Dáníẹ́lì Ní ọdun kìn-ín-ní Dáríúsì ọmọ Áhásúérésì, ẹni tí a bí ní Médíà, òun ló jẹ ọba lórí ìjọba Bábílónì Ní ọdun kìn-ín-ní ijọba rẹ̀, èmi Dáníẹ́lì fi iyè sí i láti inú ìwé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí wòlíì Jeremáyà, wá pé, àádọ́rin ọdún ni Jérúsálẹ́mù yóò fi wà ní ahoro Nígbà náà, ni mo yípadà sí Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú ààwẹ̀, aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú Mo gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́ wí pé Iwọ Olúwa , Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó ní ìfẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ó ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀ Àwa kò fetí sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ sí àwọn ọba wa, àwọn ọmọ aládé àti àwọn baba wa, àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà Olúwa ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Júdà, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù àti gbogbo Ísírẹ́lì ní gbogbo orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìsòótọ́ ọ wa sí ọ Áà! Olúwa , àwa àti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ aládé, àti àwọn baba wa, ìtìjú dé bá wa nítorí àwa ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ Olúwa Ọlọ́run wa ní àánú, ó sì ń dáríjì, bí àwa tilẹ̀ ti ṣe ọ̀tẹ̀ síi Àwa kò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run wa, a kò sì pa àwọn òfin rẹ mọ́, èyí tí ó fún wa nípasẹ̀ àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀ Gbogbo Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀ sí òfin rẹ, wọ́n ti yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n kọ̀ láti ṣe ìgbọràn sí ọ Nígbà náà ni ègún àti ìdájọ́ tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìbúra nínú òfin Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run dà sórí i wa, nítorí tí àwa ti sẹ̀ sí ọ Ìwọ ti mú ọ̀rọ̀ tí o sọ sí wa sẹ àti lórí àwọn alákòóso wa, nípa mímú kí ibi ńlá bá wa, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ọ̀run, bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù yìí Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Mósè bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ibi yìí ti dé bá wa, ṣíbẹ̀ a kò bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere Olúwa Ọlọ́run wa, nípa yíyí padà kí a kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì mọ òtítọ́ ọ rẹ Olúwa kò jáfara láti mú ibi náà wá sórí wa, nítorí Olódodo ni Olúwa Ọlọ́run wa nínú u gbogbo ohun tí ó ń ṣe ṣíbẹ̀ àwa kò ṣe ìgbọ́ran sí i Ní ìsinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, pẹ̀lú ọwọ́ agbára, tí ó fún ara rẹ̀ ní orúkọ tí ó wà títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búrurú Olúwa , ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òdodo rẹ, yí ìbínú àti ìrunú rẹ padà kúrò ní Jérúsálẹ́mù ìlú u rẹ, òkè mímọ́ rẹ Ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àìṣedéédé àwọn baba wa ti mú Jérúsálẹ́mù àti ènìyàn rẹ di ẹ̀gàn fún gbogbo àwọn tí ó yí wọn ká Nísinsinyìí, Ọlọ́run wa, gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, nítorí i tìrẹ Olúwa , fi ojú àánú wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti dahoro Tẹ́ etí rẹ sílẹ̀, Ọlọ́run, kí o gbọ́ ya ojú ù rẹ sílẹ̀, kí o sì wo ìdahoro ìlú tí a ń fi orúkọ rẹ pè Àwa kò gbé ẹ̀bẹ̀ wa kalẹ̀ níwájú u rẹ nítorí pé a jẹ́ olódodo, bí kò ṣe nítorí àánú ńlá rẹ Olúwa , fetí sílẹ̀! Olúwa , Dáríjìn! Olúwa , gbọ́ kí o sì ṣe é! Nítorí i tìrẹ, Ọlọ́run mi, má ṣe pẹ́ títí, nítorí ìlú rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọ lára Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀, tí mo sì ń gba àdúrà, tí mo ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi, tí mo sì ń mú ẹ̀bẹ̀ mi tọ Olúwa Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ rẹ Bí mo ṣe ń gba àdúrà náà lọ́wọ́, Gébúrẹ́lì ọkùnrin tí mo rí nínú ìran ìṣáájú, yára kánkán wá sí ọ̀dọ̀ mi ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́ Ó jẹ́ kí ó yé mi, ó sì wí fún mi pé, Dáníẹ́lì, mo wá láti jẹ́ kí o mọ̀ kí o sì ní òye Bí o ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní gba àdúrà, a fún ọ ní ìdáhùn kan, èyí tí mo wá láti sọ fún ọ, nítorí ìwọ jẹ́ àyànfẹ́ gidigidi Nítorí náà, gba ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò kí ìran náà sì yé ọ Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ni a pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ àti fún àwọn ìlú mímọ́ ọ rẹ láti parí ìrékọjá, láti fi òpin sí ẹ̀ṣẹ̀, láti ṣe ètùtù sí ìwà búburú, láti mú òdodo títí ayé wá, láti ṣe èdìdì ìran àti wòlíì àti láti fi òróró yan ẹni mímọ́ jùlọ Nítorí náà, mọ èyí pé Láti ìgbà tí a ti gbé ọ̀rọ̀ náà jáde wí pé kí a tún Jérúsálẹ́mù se, kí a sì tú un kọ́, títí ẹni òróró náà, alákòóso wa yóò fi dé, ó jẹ́ ọ̀ṣẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta a ó sì tún ìgboro àti yàrá rẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà ni Lẹ̀yìn ọ̀ṣẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó ké ẹni òróró náà kúrò, kò sì ní ní ohun kan Àwọn ènìyàn alákòóso tí yóò wá ni yóò pa ìlú náà àti ibi mímọ́ run Òpin yóò dé bí ìkún omi ogun yóò máa jà títí dé òpin, a sì ti pàṣẹ ìdahoro Yóò sì fi ìdí i májẹ̀mu kan múlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan Ní àárin ọ̀sẹ̀ ni yóò mú òpin bá ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ Àti lórí ìyẹ́ tẹ́ḿpìlì ni yóò dà ìríra sórí àwọn tí ó mú ìdahoro wá, títí tí òpin tí a ti pàṣẹ lórí asọnidahoro yóò fi padà fi dé bá a Àṣẹ Láti Jáde Kúrò Ní Hórébù Wọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ fún gbogbo Ísírẹ́lì ní ihà ìlà oòrùn Jọ́dánì, aginjù ní òdì kejì Súfì, ní àárin Páránì àti Tófẹ́lì, Lábánì, Hásérótì àti Dísáhábì Ní ìgbà tí ó pé ogójì ọdún, ní ọjọ́ kìn-ín-ní osù kọ́kànlá, Mósè sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run pa láṣẹ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún wọn Èyí sẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣẹ́gun Síhónì ọba àwọn Ámórì, tí ó jọba ní Hésíbónì, àti Ógù ọba Básánì ni ó ṣẹ́gun ní Édírénì, ẹni tí ó jọba ní Ásítarótù Ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì tí ó wà nínú ilẹ̀ Móábù ni Mósè ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàlàyé àwọn òfin wọ̀nyí wí pé Olúwa Ọlọ́run wa bá wa sọ̀rọ̀ ní Hórébù pé, Ẹ ti dúró ní orí òkè yìí pẹ́ tó Ẹ yípadà kí ẹ sì tẹ̀ṣíwájú ní ìrìnàjò yín lọ sí ilẹ̀ òkè àwọn ará Ámórì Ẹ tọ gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń gbé agbégbé lọ ní aginjù, ní àwọn orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní Nágéfì àti ní etí òkun, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kénánì àti lọ sí Lẹ́bánónì, títí fi dé odò ńlá Éfúrétì Wò ó, èmi tí fi ilẹ̀ yí fún un yín Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí Olúwa ti wí pé òun yóò fún àwọn baba yín fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù, àti fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn Mo wí fún-un yín nígbà náà pé, Èmi nìkan kò lè dá ẹrù u yín gbé mọ́ Olúwa Ọlọ́run yín ti sọ yín di púpọ̀ lónìí, ẹ̀yin sì ti pọ̀ bí ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run Kí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín sọ yín di púpọ̀ ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún sí i, kí ó sì bùkún un yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí Báwo ni èmi nìkan ṣe lè má a ru àjàgà àti ìsòro yín àti èdè àìyedè yín Ẹ yan àwọn ọlọgbọ́n, olóye àti àwọn ẹni àpọ́nlé, láti inú ẹ̀yà yín kọ̀ọ̀kan, èmi yóò sì fi wọ́n ṣe olórí yín Ẹ̀yin sì dá mi lóhùn wí pé, Ohun tí ìwọ ti gbérò láti ṣe n nì dára Bẹ́ẹ̀ ni mo yan àwọn aṣáájú ẹ̀yà yín, àwọn ọlọgbọ́n àti ẹni àpọ́nlé láti ṣe àkóso lórí yín gẹ́gẹ́ bí olùdarí ẹgbẹgbẹ̀rún, ọgọgọ́rùn-ún, àràádọ́ta, ẹ̀wẹ̀ẹ̀wá àti gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn ẹ̀yà Mo sì kìlọ̀ fún àwọn onídàájọ́ yín nígbà náà pé Ẹ gbọ́ èdè àìyedè tí ó wà láàrin àwọn ènìyàn an yín kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ òdodo, bóyá ẹjọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ láàrin Ísírẹ́lì sí Ísírẹ́lì ni tàbí láàrin Ísírẹ́lì kan sí àlejò Ẹ má sì se ojúṣàájú ní ìdájọ́ Ẹ ṣe ìdájọ́ ẹni ńlá àti kékeré bákan náà Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹnikẹ́ni torí pé ti Ọlọ́run ni ìdájọ́ Ẹjọ́ tí ó bá le jù fún un yín ni kí ẹ mú wá fún mi Èmi yóò sì gbọ́ ọ Nígbà náà ni èmi yóò ṣọ ohun tí ẹ ó ṣe fún un yín Nígbà náà ní a gbé ra láti Horebu, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wá, a sì la àwọn ilẹ̀ lókè Ámórì kọjá lọ dé gbogbo aṣálẹ̀ ńlá tí ó ba ni lẹ́rù nì tí ẹ̀yin ti rí, bẹ́ẹ̀ ni a sì dé Kádésì Báníyà Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, Ẹ ti dé ilẹ̀ òkè àwọn ará Ámórì, èyí tí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa Ẹ kíyèsìí, Olúwa Ọlọ́run yín ló ní ilẹ̀ náà Ẹ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín tí sọ fún un yín Ẹ má bẹ̀rù, Ẹ má sì ṣe fòyà Nígbà náà ni gbogbo yín tọ̀ mí wá wí pé, Jẹ́ kí a yan àwọn ayọ́lẹ̀wò láti yọ́ ilẹ̀ náà wò fún wa, kí wọn sì fún wa ní ìròyìn àwọn ọ̀nà tí a ó gbà àti àwọn ìlú tí a ó bá pàdé Èrò náà sì dára lójú mi, torí èyí ni mo ṣe yan àwọn ènìyàn méjìlá nínú yín, ẹnìkan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan Wọ́n sì gòkè lọ sí ilẹ̀ òkè náà, wọ́n sì wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ésíkónì, wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò Wọ́n sì mú lára èso ilẹ̀ náà wá fún wa pé, Ilẹ̀ tí ó dára ni Olúwa Ọlọ́run wa fún wa Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ gòkè lọ ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín Ẹ kùn nínú àgọ́ ọ yín, ẹ sì wí pé, Olúwa kórìíra wa, torí èyí ló fi mú wa jáde láti Éjíbítì láti fi wá lé àwọn ará Ámórì lọ́wọ́ láti pa wá run Níbo la ó lọ Àwọn arákùnrin wa ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa nípa sísọ pé, Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga jù wá lọ àwọn ìlú náà tóbi jọjọ bẹ́ẹ̀ ni odi wọn ga kan ọ̀run A tilẹ̀ rí àwọn òmìrán níbẹ̀   Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, Ẹ má ṣojo, ẹ kò sì gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú yín yóò jà fún un yín bí ó ti ṣe fún un yín ní Éjíbítì lójú ẹ̀yin tìkárayín àti ní ihà Níbẹ̀ ni ẹ ti rí i bí Olúwa Ọlọ́run yín ti gbé yín, bí baba ti í gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ lọ títí ẹ fi padà dé ibí yìí Pẹ̀lú gbogbo èyí tí mo wí, ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú u yín lọ ní gbogbo ọ̀nà an yín, nípa fífi iná ṣe amọ̀nà an yín ní òru àti ìkùukù ní ọ̀sán, láti fi àwọn ibi tí ẹ lè tẹ̀dó sí hàn yín àti àwọn ọ̀nà tí ẹ ó rìn Nígbà tí Olúwa gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra wí pé Kò sí ọ̀kan nínú ìran búburú yìí tí yóò dé ilẹ̀ rere tí mo ti búra láti fún àwọn baba ńlá a yín Bí kò ṣe Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnì Òun ni yóò wọ̀ ọ́ Èmi yóò sì fún òun àti àwọn ìran rẹ̀ ní ilẹ̀ náà tí ó ti fi ẹṣẹ̀ rẹ̀ tẹ̀ torí pé ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀lé Olúwa Torí i ti yín ni Olúwa fi bínú sí mi wí pé, Ìwọ náà kì yóò wọ ibẹ̀ bákan náà, ṣùgbọ́n Jósúà ọmọ Núnì tí ń ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ ni yóò wọ ibẹ̀ Mú un, ní ọkàn le torí pé, òun yóò ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti gba ilẹ̀ náà Àwọn èwe yín tí ẹ ṣọ pé wọn yóò kó lẹ́rú Àwọn ọmọ yín tí ko tí ì mọ rere yàtọ̀ sí búburú ni yóò wọ ilẹ̀ náà Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, ẹ yí pada sí aṣálẹ̀ tí ó wà ní ọ̀nà tí ó lọ sí òkun pupa Nígbà náà ni ẹ fèsì wí pé, Àwa ti ṣẹ̀ sí Olúwa A ó sì gòkè lọ láti jà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wa Torí náà gbogbo yín ẹ mú ohun ìjà a yín, ẹ rò pé ó rọrùn láti gòkè lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè olókè náà Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún mi pé, Sọ fún wọn, Ẹ má se gòkè lọ láti jà torí pé èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín Àwọn ọ̀ta a yín yóò sì sẹ́gun yín   Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún un yín, ẹ kò sì gbọ́, ẹ sọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa , pẹ̀lú ìgbéraga yín ẹ gòkè lọ sí ìlú olókè náà Àwọn ará Ámórì tí ń gbé ní àwọn òkè náà, dojú kọ yín bí àgbájọpọ̀ oyin Wọ́n sì lù yín bolẹ̀ látí Séírì títí dé Hómà Ẹ padà, ẹ sì sunkún níwájú Olúwa , òun kò sì fetí sí igbe ẹkún yín, Ó sì kọ etí dídi sí i yín Báyìí ni ẹ sì dúró ní Kádésì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ṣe Síléètì Òfin Bí i Ti Ìṣáájú Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, Gbé síléètì òkúta méjì bí i ti àkọ́kọ́ kí o sì gòkè tọ̀ mí wá Kí o sì tún figi kan àpótí kan Èmi yóò sì tún ọ̀rọ̀ tí ó wà lórí síléètì àkọ́kọ́ tí o fọ́ kọ sórí rẹ̀ Kí o sì fi wọ́n sínú àpótí náà Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kaṣíà, mo sì gbẹ́ síléètì òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú síléètì méjèèjì lọ́wọ́ mí Olúwa tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí síléétì wọ̀nyí Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrin iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀ Olúwa sì fi wọ́n fún mi Mo sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, mo sì ki àwọn síléètì òkúta náà sínú àpótí tí mo ti kàn, bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi, wọ́n sì wà níbẹ̀ di ìsinsin yìí Mo tún dúró ní orí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, bí mo ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́, Olúwa sì gbọ́ tèmi ní àkókò yìí bákan náà Kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láti run yín Olúwa sọ fún mi pé, Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn báà lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn Nísinsin yìí ìwọ Ísírẹ́lì, kín ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ọkan àti àyà rẹ, àti láti máa kíyèsí àṣẹ àti ìlànà Olúwa tí mo ń fún ọ lónìí, fún ire ara à rẹ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀ Ṣíbẹ̀ Olúwa sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀ èdè títí di òní Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, kí ẹ má sì se jẹ́ olóríkunkun mọ́ láti òní lọ Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojú ṣàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àlejò, Óun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn Ẹ gbọ́dọ̀ fẹ́ràn àwọn àlejò, torí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àlejò rí ní Éjíbítì Ẹ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín Ẹ dì í mú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀ Òun ni ìyìn in yín, Òun sì ni Ọlọ́run yín, tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá àti ohun ẹ̀rù, tí ẹ fojú ara yín rí Àádọ́rin péré ni àwọn baba ńlá a yín tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì, ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín ti mú un yín pọ̀ síi ní iye bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run Fẹ́ràn Ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sì pa ìfẹ́ rẹ̀, ìlànà rẹ̀, òfin rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ ní ìgbà gbogbo Ẹ rántí lónìí pé kì í ṣe àwọn ọmọ yín, ni ó rí ìbáwí Olúwa Ọlọ́run yín títóbi rẹ̀, ọwọ́ agbára rẹ̀, nína ọwọ́ rẹ̀ iṣẹ́ àmì rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe ní àárin àwọn ará Éjíbítì Sí Fáráò ọba Éjíbítì àti gbogbo orílẹ̀ èdè rẹ̀ Ohun tí ó ṣe sí àwọn jagunjagun Éjíbítì, sí kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́sin rẹ̀ bí ó se rì wọ́n sínú òkun pupa, bí wọ́n ṣe ń lé e yín tí Olúwa fi pa wọ́n run pátapáta títí di òní olónìí yìí Kì í ṣe àwọn ọmọ yín ni ó rí ohun tí ó ṣe fún un yín ní ihà, títí ẹ fi dé ìhín yìí, ohun tí ó ṣe sí Dátanì àti Ábírámù, àwọn ọmọ Élíábù, ẹ̀yà Rúbẹ́nì, bí ilẹ̀ ti lanu ní ojú gbogbo ará Ísírẹ́lì tí ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ìdílé wọn, gbogbo àgọ́ ọ wọn àti gbogbo ohun alààyè tí ó jẹ́ tiwọn Ṣùgbọ́n ojú u yín gan an ni ó rí gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí tí Olúwa ti ṣe Nítorí náà, ẹ kíyèsí gbogbo àṣẹ tí mo ń fún un yín lónìí, kí ẹ ba à lè lágbára àti lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí ẹ ó la Jọ́dánì kọjá lọ Kí ẹ ba à lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa ti búra fún àwọn baba ńlá a yín, láti fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin Ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà kò rí bí ilẹ̀ Éjíbítì, níbi tí ẹ ti wá, níbi tó jẹ́ wí pé ẹṣẹ̀ yín ni ẹ fi ń rìn lọ bominrin irúgbìn tí ẹ gbìn bí oko ẹ̀fọ́ Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí ẹ ó la Jọ́dánì kọjá láti gbà, jẹ́ ilẹ̀ olókè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí òjò ń rọ̀ sí latọ̀run Ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń mójútó ni, ojú Olúwa Ọlọ́run yín sì ń fi ìgbà gbogbo wà lórí rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún dé òpin ọdún Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́ràn sí àṣẹ tí mo fún un yín lónìí tọkàntọkàn tí ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì sìn ín, pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn yín nígbà náà, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ ẹ yín lákòókò rẹ̀, àti òjò àkọ́rọ̀ àti ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ ba à lè kórè oúnjẹ yín wọlé àní wáìnì tuntun àti òróró Èmi yóò mú kí koríko hù lórí ilẹ̀ yín fún àwọn ohun ọ̀sìn in yín, ẹ ó sì jẹ, ẹ ó sì yó Ẹ ṣọ́ra, kí a má bàá tàn yín jẹ láti yípadà kí ẹ sì sin Ọlọ́run mìíràn àti láti máa foríbalẹ̀ fún wọn Nígbà náà ni ìbínú Olúwa yóò sì ru sí i yín, Òun yóò ti ìlẹ̀kùn ọ̀run kí òjò má baà rọ̀, ilẹ̀ kì yóò sì so èso kankan, ẹ ó sì ṣègbé ní ilẹ̀ rere tí Olúwa fi fún un yín Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà a yín, àti ọkàn an yín, ẹ so wọ́n bí àmì sórí ọwọ́ ọ yín, kí ẹ sì ṣo wọ́n mọ́ iwájú orí i yín Ẹ máa fí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí Ẹ kọ wọ́n sí férémù ìlẹ̀kùn yín, àti ẹnu ọ̀nà àbáwọlé e yín Kí ọjọ́ ọ yín àti ti àwọn ọmọ yín lè pọ̀ ní ilẹ̀ tí Olúwa ti búra láti fifún àwọn baba ńlá a yín, ní ìwọ̀n ìgbà tí ọ̀run wà lókè tí ayé sì ń bẹ ní ìṣàlẹ̀ Bí ẹ bá farabalẹ̀ kíyèsí àwọn òfin tí mo ń fún un yín, láti tẹ̀lé Láti fẹ́ Olúwa Ọlọ́run yín, láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti láti dìí mú ṣinṣin Olúwa yóò sì lé gbogbo orílẹ̀ èdè wọ̀nyí kúrò níwájú u yín Ẹ ó sì gba orílẹ̀ èdè tí ó lágbára tí ó sì tóbi jù yín lọ Gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹṣẹ̀ ẹ yín tẹ̀ ni yóò jẹ́ tiyín, ilẹ̀ ẹ yín yóò gbilẹ̀ láti aṣálẹ̀ dé Lẹ́bánónì, àti láti odò Yúfúrátè dé òkun ìwọ̀ oòrùn Kò sí ẹni náà tí yóò lè kò yín lójú ìjà, Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi ẹ̀rù àti ìwárìrì i yín sórí gbogbo ilẹ̀ náà bí ó ti ṣèlérí fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá lọ Ẹ kíyèsí i, mo fi ìbùkún àti ègún lélẹ̀ níwájú u yín lónìí ìbùkún ni, bí ẹ bá pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí mo ń fún un yín lónìí mọ́ Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tíì mọ̀ Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín ba ti mú un yín dé ilẹ̀ náà tí ẹ ń wọ̀ láti gbà, kí ẹ kéde àwọn ìbùkún náà ní orí òkè Gérísímù, kí ẹ sì kéde àwọn ègún ní orí òkè Ébálì Bí ẹ ti mọ̀ pé àwọn òkè wọ̀nyí wà ní ìkọjá a Jọ́dánì ní apá ìwọ̀ oòrùn lójú ọ̀nà lọ sí ìhà ìlà oòrùn, ní ẹ̀gbẹ́ igbó igi Mórè ńlá, ní ilẹ̀ àwọn ará a Kénánì, tí wọ́n ń gbé ní aginjù, ni agbégbé Gígálì Ẹ ti ṣetan láti la Jọ́dánì kọjá láti lè gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín Nígbà tí ẹ bá gbà á, tí ẹ bá sì ń gbé ibẹ̀, ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń gbọ́ran sí gbogbo ìlànà àti òfin tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí Ibi Ìsìn Kan Ṣoṣo Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà àti òfin tí ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra láti máa tẹ̀lé, ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, fi fún un yín láti gbà ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá fi wà lórí ilẹ̀ náà Gbogbo ibi gíga àwọn òkè ńlá, àti òkè kéékèèkéé àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀ níbi tí àwọn orílẹ̀ èdè tí ẹ ó lé jáde, tí ń sin òrìṣà wọn ní kí ẹ mú kúrò pátapáta Ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, ẹ bi òpó ìsìn wọn subú, kí ẹ sì sun òpó òrìṣà wọn ní iná Ẹ gé gbogbo ère òrìṣà wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn rẹ́ ní gbogbo ààyè wọn Ẹ kò gbọdọ̀ sin Olúwa Ọlọ́run yín bí i tiwọn Ṣùgbọ́n ẹ wá ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn láàrin àwọn ìran yín, láti fi orúkọ rẹ̀ ṣíbẹ̀ bí i ibùgbé rẹ̀ Ibẹ̀ ni kí ẹ lọ Níbẹ̀ ni kí ẹ mú ọrẹ síṣun àti ẹbọ yín wá, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àwọn ẹ̀jẹ́ yín, ọrẹ àtinúwá yín, àti àwọn àkọ́bí gbogbo màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín Níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, kí ẹ̀yin àti ìdílé yín jẹun kí ẹ sì yó, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín Ẹ má ṣe ṣe bí a tí ṣe lónìí yìí, tí olúkúlùkù ń ṣe ohun tí ó wù ú Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti dé ibi ìsinmi, àti ibi ogún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín Ṣùgbọ́n ẹ ó la Jọ́dánì kọjá, ẹ ó sì máa gbé ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín bí ìní, yóò sì fún un yín ní ìsinmi, kúrò láàrin àwọn ọ̀ta a yín, tí ó yí i yín ká, kí ẹ báà lè máa gbé láìléwu Níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀ Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ síṣún, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, ẹ̀yin, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, ìránṣẹ́-bìnrin àti ìránṣẹ́-kùnrin yín, àti àwọn Léfì láti ìlú u yín, tí wọn kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn Ẹ sọ́ra kí ẹ má ṣe rú ẹbọ siṣun yín ní ibikíbi tí ẹ̀yin fẹ́ Ibi tí Olúwa yóò yàn láàrin àwọn ẹ̀yà a yín nìkan ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ yín, kí ẹ sì máa kíyèsí ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín níbẹ̀ Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ẹ lọ pa àwọn ẹran yín ní èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín, kí ẹ sì jẹ ẹran náà tó bí ẹ ti fẹ́, bí ẹ ti ń ṣe sí àgbọ̀nrín àti èṣúó, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fi fún un yín, àti ẹni mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ nínú àwọn ẹran náà Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn, ẹ dàá sílẹ̀ bí omi Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àkọ́bí àwọn màlúù yín, tàbí ti ewúrẹ́ ẹ yín, ohunkóhun tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ àtinúwá, tàbí ẹ̀bùn pàtàkì ní ìlú ẹ̀yin tìkárayín Bí kò ṣe kí ẹ jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín, yóò yàn ìwọ, àwọn ọmọkùnrin rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ, àwọn ìránṣẹ́-kùnrin àti ìránṣẹ́-bìnrin rẹ àti àwọn Léfì láti ìlú u yín kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Léfì, ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá ń gbé ní ilẹ̀ ẹ yín Bí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti fẹ́ agbègbè e yín bí ó ti ṣe ìlérí, fún un yín, tí ẹ sì wí pé, àwa yóò jẹ ẹran, nítorí tí ọkàn wa fẹ́ jẹran Ẹ jẹ ẹran náà bí ẹ tí fẹ́ Bí ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín bá yàn fún orúkọ rẹ̀ bá jìnnà sí i yín, kí ẹ pa màlúù tàbí ewúrẹ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín tí fún un yín, bí mo ti pàṣẹ fún un yín ní ìlú u yín, ẹ lè jẹ ẹ́ bí ẹ ti fẹ́ Ẹ jẹ wọ́n bí ẹ ó ti jẹ èṣúó tàbí àgbọ̀nrín, ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́ Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn, nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí, ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀mí pọ̀ mọ́ ẹran Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, ẹ dà á sílẹ̀ bí omi Ẹ má ṣe jẹ ẹ́, kí ó báà lè dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín, tí ń bọ̀ lẹ́yìn in yín Nígbà yí ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà lójú Olúwa Ẹ mú àwọn ohun tí ẹ yà sọ́tọ̀ àti àwọn ẹ̀jẹ́ yín, kí ẹ sì lọ síbi tí Olúwa yóò yàn Ẹ fi ọrẹ síṣun yín kalẹ̀ lórí i pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run yín, àti ẹran àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ Ẹ̀jẹ̀ ọrẹ yín ni ki ẹ dà sí pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ ẹran Ẹ kíyèsára láti máa gbọ́ràn sí gbogbo ìlànà tí mò ń fún un yín, kí o báà dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín nígbà gbogbo, nítorí pé nígbà náà ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà níwájú Olúwa Ọlọ́run yín Olúwa Ọlọ́run yín yóò gé àwọn orílẹ̀ èdè tí ẹ fẹ́ lé kúrò tí ẹ sì fẹ́ gba ilẹ̀ wọn kúrò níwájú u yín Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ bá tí lé wọn jáde tí ẹ sì ń gbé ilẹ̀ wọn Lẹ́yìn ìgbà tí a bá ti pa wọ́n run níwájú u yín, ẹ sọ́ra kí ẹ má baà bọ́ sínú àdánwò nípa bíbéèrè nípa àwọn òrìṣà wọn wí pé, Báwo ni àwọn orílẹ̀ èdè yìí ṣe ń sin àwọn òrìṣà wọn Àwa náà yóò ṣe bẹ́ẹ̀ Ẹ má ṣe sin Olúwa Ọlọ́run yín bí àwọn, torí pé, nípa sínsin ọlọ́run wọn, wọ́n ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìríra tí Ọlọ́run kórìíra Wọ́n ń dáná ṣun àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn láti fi rúbọ sí ère òrìṣà wọn Ẹ rí i pé ẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tí mo ti pàṣẹ fún un yín Ẹ má ṣe fi kún un, ẹ má sì se yọ kúró níbẹ̀ Sísin Àwọn Ọlọ́run Mìíràn Bí wòlíì tàbí aláṣọtẹ́lẹ̀ nípa àlá lílá bá farahàn láàrin yín, tí ó sì ń kéde iṣẹ́ àmì tàbí iṣẹ́ ìyanu, bí iṣẹ́ àmí tàbí iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ṣẹ tí òun sì wí pé, ẹ wá ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn kí ẹ sì jẹ́ kí a máa sìn wọ́n, ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ tàbí àlá náà, Olúwa Ọlọ́run yín ń dán an yín wò ni, láti mọ̀ bóyá ẹ fẹ́ràn rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn an yín Olúwa Ọlọ́run yín ni kí ẹ tẹ̀lé, Òun ni kí ẹ bọlá fún, ẹ pa òfin rẹ̀ mọ́ kí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀ ẹ sìn ín, kí ẹ sì dì í mú ṣinṣin Wòlíì náà tàbí alálàá náà ni kí ẹ pa, nítorí pé wàásù ìṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú yín jáde láti Éjíbítì wá, tí ó sì rà yín padà lóko ẹrú Ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lójú ọ̀nà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín láti máa rìn Ẹ gbọdọ̀ yọ ibi náà kúrò láàrin yín Bí arákùnrin tìrẹ gan-an ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin, aya tí o fẹ́ràn jù, tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bá tàn ọ́ jẹ níkọ̀kọ̀ wí pé jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn, àwọn tí ó wà láyìíka yín, yálà wọ́n jìnnà tàbí wọ́n wà nítòsí, láti òpin ilẹ̀ kan dé òmíràn) Má ṣe fetí sí i, má sì dá sí i, má ṣe dáàbò bò ó O gbọdọ̀ pa á ni Ìwọ gan an ni kí o kọ́kọ́ gbé ọwọ́ rẹ lé e tàbí pa á, lẹ́yìn náà kí gbogbo àwọn yóòkù ṣù bò ó láti pa á Sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí pé ó gbìyànjú láti fà ọ́ kúrò lẹ́yìn Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó mú ọ jáde ti Éjíbítì wá kúrò ní oko ẹrú Gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, kò sì sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí yóò dán irú ibi bẹ́ẹ̀ wò mọ́ Bí ẹ bá gbọ́ tí a sọ nípa èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín láti máa gbé, pé àwọn ènìyàn búburú, ti farahàn láàrin yín, tí ó sì ti mú kí àwọn ènìyàn ìlú wọn sìnà lọ, tí wọ́n wí pé, Ẹ jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn, Kí ẹ wádìí, ẹ bèèrè, kí ẹ sì tọpinpin ọ̀rọ̀ náà dájúṣáká, bí ó bá jẹ́ òtítọ́ ni, tí ó sì hàn dájú pé ìwà ìríra yìí ti ṣẹlẹ̀ láàrin yín Gbogbo àwọn tí ó ń gbé ìlú náà ni kí ẹ fi idà run pátápátá Ẹ run ún pátapáta, àti ènìyàn àti ẹran ọ̀sìn inú rẹ̀ Ẹ kó gbogbo ìkógun ìlú náà, sí àárin gbogbo ènìyàn, kí ẹ ṣun ìlú náà àti gbogbo ìkógun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun sísun sí Olúwa Ọlọ́run rẹ Ó gbọdọ̀ wà ní píparun láéláé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ tún-un kọ A kò gbọdọ̀ rí ọ̀kan nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun wọ̀n-ọn-nì lọ́wọ́ ọ yín, kí Olúwa ba à le yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀, yóò sì ṣàánú fún un yín, yóò sì bá a yín kẹ́dùn, yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, bí ó ti fìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá yín Nítorí pé ẹ gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí mo ń fún un yín lónìí yìí tí ẹ sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ̀ Oúnjẹ Tí Ó Mọ́ Àti Èyí Tí Kò Mọ́ Ọmọ Olúwa Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́ nítorí náà, ẹ má ṣe ya ara yín ní abẹ Ẹ má ṣe gé irun iwájú orí i yín nítorí òkú Nítorí pé ènìyàn mímọ́ ní ẹ jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run ti yàn yín láti jẹ́ ìṣúra iyebíye rẹ̀ Ẹ má ṣe jẹ ohun ìríra kankan Àwọn wọ̀nyí ni ẹranko tí ẹ lè máa jẹ màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́, àgbọ̀nrín, èsúó, ẹtu, àgóró, ẹfọ̀n, ìgalà àti àgùntàn igbó Ẹ lè jẹ gbogbo ẹranko tí pátakò ẹṣẹ̀ rẹ̀ kì í se méjì tí ó sì tún jẹ àpọ̀jẹ Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ nínú gbogbo ẹran tí ń jẹ àpọ̀jẹ tí ó sì tún ya pátakò ẹṣẹ̀ tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ni ràkunmí, ehoro, àti ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n wọn kò la pátakò, ẹṣẹ̀ a kà wọ́n sí àìmọ́ fún un yín Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ àìmọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ya pátakò ẹṣẹ̀, kì í jẹ àpọ̀jẹ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú rẹ̀ Nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ èyíkéyí tí ó ní lẹbẹ àti ìpẹ́ Ṣùgbọ́n èyíkéyí tí kò bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́, ẹ má ṣe jẹ ẹ́, nítorí pé àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún un yín Ẹ lè jẹ ẹyẹ tí ó bá mọ́ Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ní ẹ kò gbọdọ̀ jẹ idì, igún, àkàlà, onírúurú àṣá àti àṣá alátagbà, onírúurú ẹyẹ ìwò, ògòǹgò, òyo, pẹ́pẹ́yẹdò àti onírúurú àwòdì, onírúurú òwìwí, òwìwí-ọ̀dàn, idì-okùn, ẹyẹ-àkọ̀, òòdẹ̀, onírúurú ẹyẹ odò mìíràn, atọ́ka àti àdán Àti gbogbo kòkòrò tí ń fò tí wọ́n ń kọ́wọ̀ọ́ rín jẹ́ aláìmọ́ fun un yín, ẹ má ṣe jẹ wọ́n Ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ èyíkéyí ẹ̀dá abìyẹ́ tí ó bá mọ́ Ẹ má ṣe jẹ ohun tí ó ti kú sílẹ̀ Ẹ lè fún àwọn àjèjì tí ń gbé ní èyíkéyí nínú ìlú yín Òun lè jẹ ẹ́ tàbí kí ẹ tà á fún àwọn àjèjì Ṣùgbọ́n ènìyàn mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́ Má ṣe ṣe ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀ Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń fi ìdá kan nínú mẹ́wàá nínú irè oko yín lọ́dọọdún pamọ́ sí apákan Ẹ jẹ ìdámẹ́wàá, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àti àkọ́bí àwọn màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín, níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, ní ibi tí yóò yàn bí ibùgbé orúkọ rẹ̀ Kí ẹ lè kọ́ bí a ṣé ń bọlá fún Olúwa Ọlọ́run yín nígbà gbogbo Bí ibẹ̀ bá jìn tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì ti bùkún fún ọ, tí o kò sì le ru àwọn ìdámẹ́wàá rẹ Ẹ pààrọ̀ àwọn ìdámẹ́wàá yín sówó, ẹ mú owó náà lọ sí ibi tí Olúwa yóò yàn Fi owó náà ra ohunkóhun tí o bá fẹ́, màlúù, àgùntàn, wáìnì, tàbí ọtí líle, tàbí ohunkóhun tí o bá fẹ́ Kí ìwọ àti ìdílé rẹ sì jẹ ẹ́ níwájú Olúwa níbẹ̀ kí ẹ sì máa yọ̀ Ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Léfì tí ó ń gbé nì ilú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín kan tàbí ogún kan tí í se tiwọn Ní òpin ọdún mẹ́tamẹ́ta, ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá irè oko àwọn ọdún náà, kí ẹ kó wọn jọ ní ìlú yín Kí àwọn Léfì àti àwọn àlejò, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé ìlú yín lè wá, kí wọn sì jẹ kí wọn sì yó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ leè bùkún fún ọ, nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ Ọdún Ìyọ̀ǹda Àti Ìdáríjì Ní òpin ọdún méjeméje, ẹ gbọdọ̀ máa yọ̀ǹda àwọn gbéṣè Báyìí ni kí ẹ máa ṣe é Gbogbo ẹni tí wọ́n jẹ ní gbéṣè gbọdọ̀ fojú fo gbésè tí ó ti yá ará Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀ Kò gbọdọ̀ béèrè ohun náà, lọ́dọ̀ ará Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀ tàbí lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀ nítorí pé a ti kéde àkókò Olúwa láti fojú fo gbésè Ẹ lè béèrè ìsanpadà lọ́dọ̀ àjòjì Ṣùgbọ́n ẹ fagi lé gbéṣè yóòwù kó jẹ́ tí arákùnrin yín jẹ yín Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò tọ́ sí nínú un yín, nítorí pé Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ilẹ̀ náà tí ó ń mú un yín lọ láti gbà bí ìní yín Kìkì bí ẹ bá gbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín tí ẹ sì kíyèsára láti máa rìn nínú gbogbo àṣẹ wọ̀nyí, tí èmi ń pa fún un yín lónìí Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín bí ó ti ṣèlérí, ẹ̀yin yóò sì máa yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ẹ kì yóò sì tọrọ Ẹ ó ṣàkóso ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè, ṣùgbọ́n kò sí orílẹ̀ èdè tí yóò lè jọba lé e yín lórí Bí talákà kan bá wà láàrin àwọn arákùnrin yín ní èyíkèyí àwọn ìlú, ilẹ̀ náà tí Olúwa yín yóò fún un yín Ẹ má ṣe se àìláànú bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe háwọ́ sí arákùnrin yín tí ó jẹ́ tálákà Ṣùgbọ́n ẹ lawọ́ kí ẹ sì fi tọkàntọkàn yá wọn ní ohun tí wọ́n nílò Ẹ sọ́ra kí èrò búburú kan má ṣe sí nínú àyà rẹ wí pé, Ọdún kéje tí í ṣe ọdún ìyọ̀ǹda gbésè ti súnmọ́ nípa bẹ́ẹ̀, ojú rẹ a sì burú sí arákùnrin rẹ talákà, tí ìwọ kò sì fun ní nǹkan, o kò sì fun ní nǹkan kan Òun a si kígbe pe olúwa nitori rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ Fún un tọkàntọkàn, láì sí ìkùnsínú, nítorí èyí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkun fún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, àti gbogbo ìdáwọ́lé rẹ A kò lè fẹ́ tálákà kù ní ilẹ̀ náà ní ìgbà gbogbo, mo pàṣẹ fún un yín láti lawọ́ sí àwọn arákùnrin yín, sí àwọn talákà àti sí àwọn aláìní, ní ilẹ̀ ẹ yín Bí Hébérù ara yín kan, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin bá ta ara rẹ̀ fún ọ, tí ó sì sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà Ní ọdún kéje, jẹ́ kí ó di òmìnira Nígbà tí ó bá dá a sílẹ̀ má ṣe jẹ́ kí ó lọ lọ́wọ́ òfo Fi tọkàntọkàn fún un láti inú agbo ewúrẹ́ rẹ, ilẹ̀ ìpakà rẹ, àti ibi ìfúntí rẹ Fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti bùkún fún ọ tó Ẹ rántí pé ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ní Éjíbítì, Olúwa Ọlọ́run yín sì rà yín padà, ìdí nìyí tí mo fi pa àṣẹ yìí fún un yín lónìí Ṣùgbọ́n bí ìránṣẹ́ rẹ bá sọ fún ọ pé, Èmi kò fẹ́ fi ọ́ sílẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ràn ìwọ àti ìdílé rẹ, tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn, kí ìwọ kí ó mú ìlu kan lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn, yóò sì di ẹrú rẹ láéláé Bẹ́ẹ̀ náà ni kí o ṣe sí ìránṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ Má ṣe kà á sí ohun ìnira láti dá ẹrú rẹ sílẹ̀, nítorí ìsìnrú rẹ̀ fún ọ, ní ọdún mẹ́fà náà tó ìlọ́po méjì iṣẹ́ alágbàṣe, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ Gbogbo àkọ́bí tí o jẹ́ akọ nínú agbo màlúù rẹ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún Olúwa , àti nínú agbo ewúrẹ́ bákan náà Ẹ má ṣe fi àkọ́bí màlúù yín ṣiṣẹ́ rárá Má ṣe rẹ́ irun àkọ́bí àgùntàn rẹ pẹ̀lú Ní ọdọọdún ni kí ìwọ àti ìdílé rẹ máa jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbi tí Òun yóò yàn Bí ẹran ọ̀ṣìn kan bá ní àbùkù bóyá ó yarọ, tàbí fọ́jú, tàbí tí ó ní èyíkèyìí àbùkù tó burú Ẹ kò gbọdọ̀ fi rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín Ẹ jẹ ẹ́ ní ìlú u yín Àti ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́ bí ìgbà tí a ń jẹ èsúó tàbí àgbọ̀nrín Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ Ẹ dà á síta bí omi Àjọ Ìrékọjá Ẹ kíyèsí oṣù Ábíbù, kí ẹ sì máa ṣe àjọ̀dún ìrékọjá ti Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí pé ní oṣù Ábíbù yìí ni ó mú un yín jáde ní Éjíbítì lóru Ẹ fi ẹran kan rúbọ bí ìrékọjá sí Olúwa Ọlọ́run yín láti inú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo màlúù yín ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀ Ẹ má ṣe jẹ ẹ́ pẹ̀lú u àkàrà tí a fi ìwúkàrà ṣe, ṣùgbọ́n ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà ìpọ́njú, nítorí pé pẹ̀lú ìkánjú ni ẹ kúrò ní Éjíbítì kí ẹ báà lè rántí ìgbà tí ẹ kúrò ní Éjíbítì ní gbogbo ọjọ́ ayé e yín Kí a má ṣe rí ìwúkàrà ní ọ̀dọ̀ ọ yín nínú ilẹ̀ ẹ yín fún ọjọ́ méje Ẹ má ṣe jẹ́ kí nǹkan kan sẹ́kù nínú ẹran tí ẹ ó fi rúbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní di àárọ̀ ọjọ́ kéjì Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ìrékọjá náà ní ìlúkílùú kankan, tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín bí kò ṣe ibi tí yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀, níbẹ̀ ni ki ẹ ti ṣe ìrúbọ ìrékọjá náà ní ìrọ̀lẹ́ nígbà tí òòrùn bá ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránti ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì Ẹ ṣun ún kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn Ní àárọ̀, kí ẹ padà sí àgọ́ ọ yín Ọjọ́ mẹ́fà ní kí ẹ fí jẹ àkàrà aláìwú, ní ọjọ́ kéje, ẹ pe àjọ kan fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan Ka ọ̀ṣẹ̀ méje láti ìgbà tí ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà Nígbà náà ni kí ẹ se àjọ̀dún ọ̀ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, nípa pípèṣè ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn ní ibùgbé fún orúkọ rẹ̀ ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrú u yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn Léfì tí ó wà ní ìlú u yín, àti àwọn àlejò, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé àárin yín Ẹ rántí pé ẹ ti jẹ́ ẹrú ní Éjíbítì rí, nítorí náà ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí dáradára Ẹ ṣe ayẹyẹ àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá ti kórè oko yín tí ẹ ti pakà tí ẹ sì ti fún ọtí tán Ẹ máa yọ̀ ní àkókò àjọ̀dún un yín, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín, àti àwọn Léfì, àwọn àjòjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó tí ń gbé ní àwọn ìlú u yín Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi se ayẹyẹ fún Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí Olúwa yóò yàn Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín ní gbogbo ìkórè e yín, àti ní gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ yín, ayọ̀ ọ yín yóò sì kún Ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún ni gbogbo àwọn ènìyàn an yín gbọdọ̀ farahàn níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn Níbi àpèjẹ àkàrà àìwú, níbi àjọ ọ̀ṣẹ̀, àti àjọ àgọ́ ìpàdé Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ wá ṣíwájú Olúwa lọ́wọ́ òfo Olúkúlùkù u yín gbọdọ̀ mú ẹ̀bùn wá bí Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún fún un tó Ẹ yan àwọn adájọ́ àti àwọn olóyè fún ẹ̀yà a yín kọ̀ọ̀kan, ní gbogbo ìlú tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín, wọ́n sì gbọdọ̀ máa fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn Ẹ má ṣe yí ẹjọ́ po, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe ojúṣàájú Ẹ má ṣe gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọgbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ òdodo jẹ́ Ẹ tẹ̀lé ìdájọ́ òtítọ́ àní ìdájọ́ òtítọ́ nìkan, kí ẹ báà lè gbé kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín Ẹ má ṣe ri òpó òrìṣà áṣérà ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ tí ẹ ti mọ fún Olúwa Ọlọ́run yín Ẹ kò gbọdọ̀ gbé òkúta òrìṣà gbígbẹ́ kan kalẹ̀ fún ara yín, nítorí èyí ni Olúwa Ọlọ́run yín kórìíra Àwọn ilé ẹjọ́ Ẹ má ṣe fi màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù, tàbí àbàwọ́n rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí ìríra ni èyí yóò jẹ́ fún un Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó ń gbé láàrin yín ní èyíkéyìí ìlú wọ̀n-ọn-nì, tí Olúwa fún un yín bá ń ṣe ibi ní ojú Olúwa Ọlọ́run yín, ní ríré májẹ̀mú rẹ̀ kọjá, èyí tí ó lòdì sí òfin mi, ó ń sin ọlọ́run mìíràn, ó ń foríbalẹ̀ fún wọn àní sí òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí èyí sì dé etíìgbọ́ ọ yín, kí ẹ wádìí ọ̀rọ̀ náà dájúdájú Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ tí ó sì hàn gbangba pé ó ti ṣe ohun ìríra yìí, ní Ísírẹ́lì Ẹ mú ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ti ṣe ibi yìí wá sí ẹnu ọ̀nà ibodè ìlú u yín, kí ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa Lẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó pa ọkùnrin náà tí ó yẹ láti kú, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe pànìyàn nípaṣẹ̀ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo Àwọn ẹlẹ́rìí ni kí ó kọ́kọ́ gbọ́wọ́ lé e láti pa á Lẹ́yìn èyí ni kí gbogbo ènìyàn dáwọ́jọ láti pa á Nípa báyìí, ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárin yín Bí ẹjọ́ bá wá sí ilé ẹjọ́ ọ yín tí ó nira jù láti dá yálà ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni, ọ̀ràn dídá tàbí ìkanni-lábùkù Ẹ mú wọn lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà tí í ṣe Léfì, àní sí ọ̀dọ̀ adájọ́ tí ó wà fún ìgbẹ́jọ́ ní ìgbà náà Ẹ béèrè lọ́wọ́ wọn, wọn yóò sì ṣe ìdájọ́ Ẹ gbọdọ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bí ìpinnu tí wọ́n fún un yín pé kí ẹ ṣe Ẹ ṣe bí òfin tí wọ́n kọ́ ọ yín, àti ìpinnu tí wọ́n fún un yín Ẹ má ṣe yípadà sọ́tùn ún tàbí sósì, kúrò nínú ohun tí wọ́n sọ fún un yín Ọkùnrin náà tí ó bá ṣe àìbọ̀wọ̀ fún adájọ́ tàbí àlùfáà tí ó ń se iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run yín, níbẹ̀ ni kí ẹ pa á Nípa báyìí ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárin yín Gbogbo ènìyàn ni yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, wọn kò sì ní ṣe àìgbọ́ràn mọ́ Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín, tí ẹ sì ti gba ilẹ̀ náà, tí ẹ sì ń gbé inú un rẹ̀, tí ẹ sì wá sọ pé, Ẹ jẹ́ kí a yan ọba tí yóò jẹ lé wa lórí bí i ti àwọn orílẹ̀ èdè tí ó yí wa ká Ẹ ríi dájú pé ọba tí Olúwa Ọlọ́run yín yàn fún un yín ní ẹ yàn Ó gbọdọ̀ jẹ́ láàrin àwọn arákùnrin yín Ẹ má ṣe fi àjòjì jọba lórí i yín àní ẹni tí kì í ṣe arákùnrin ní Ísírẹ́lì Ṣíwájú sí i, ọba náà kò gbọdọ̀ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsin jọ fún ara rẹ̀, tàbí kí ó rán àwọn ènìyàn náà padà sí Éjíbítì láti wá àwọn ẹsin sí i, nítorí pé Olúwa ti sọ fún un yín pé, Ẹ kò gbọdọ̀ tún padà lọ ní ọ̀nà náà mọ́ Kò gbọdọ̀ kó aya jọ, kí ọkàn rẹ̀ má bàá yapa kúrò Kò gbọdọ̀ kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ Nígbà tí ó bá dé orí oyè ilé ọba rẹ̀ kí ó ṣe àdàkọ àwọn òfin wọ̀nyí sí inú ìwé fún ara rẹ̀, láti inú un ti àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì Èyí gbọdọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ máa kà wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, àti láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà an rẹ̀ tọkàntọkàn Kí ó má baà lérò pé òun sàn ju àwọn arákùnrin rẹ̀ yóòkù lọ, kí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ yípadà kúrò nínú òfin wọ̀nyí sí ọ̀tún tàbí sósì Bẹ́ẹ̀ ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jọba pẹ́ títí ní Ísírẹ́lì Ọrẹ Fún Àwọn Àlùfáà Àti Àwọn Ọmọ Léfì Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, àní gbogbo ẹ̀yà Léfì, wọn kì yóò ní ìpín tàbí ogún láàrin Ísírẹ́lì, wọn yóò máa jẹ nínú ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa , nítorí òun ni ogún un tiwọn Wọn kì yóò ní ìní láàrin àwọn arákùnrin wọn Ọlọ́run ni yóò jẹ́ ìní i tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti se ìlérí fún wọn Gbogbo èyí ni yóò jẹ́ ìpín àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó fi akọ màlúù tàbí àgùntàn rúbọ wọn yóò fi èjìká àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì àti gbogbo inú fún àlùfáà Àkọ́so irúgbìn ọkà rẹ, ti wáìnì àti ti òróró rẹ, àti àkọ́rẹ́ irun àgùntàn rẹ ni ìwọ yóò fi fún wọn Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n àti àwọn ọmọ wọn láti inú gbogbo ẹ̀yà láti dúró àti láti ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa títí láé Tí ọmọ Léfì kan bá sì wá láti ibikíbi nínú àwọn ìlú u yín ní Ísírẹ́lì, níbi tí ó ń gbé ṣe àtìpó, tí ó sì wá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀ sí ibi tí Ọlọ́run yóò yàn Nígbà náà ni ó lè máa ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Léfì arákùnrin rẹ̀ ti ń dúró ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú Olúwa níbẹ̀ Wọn yóò ní ìpín kan láti jẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti gba owó nípa títa ogún baba rẹ̀ Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ìríra àwọn orílẹ̀ èdè náà tí ó wà níbẹ̀ Má se jẹ́ kí a rí ẹnikẹ́ni láàrin yín tí ó fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin la iná já kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ ṣe àyẹ̀wò, tàbí ṣẹ́ oṣó, tàbí túmọ̀ àwọn àmì nǹkan tí ń bọ̀, tàbí àjẹ́, tàbí afògèdè, tàbí jẹ́ a bá iwín gbìmọ̀ tàbí oṣó tàbí abókúsọ̀rọ̀ Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìríra sí Olúwa , àti nítorí àwọn ìwà ìríra wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi lé àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí jáde kúrò níwájú rẹ O ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ Àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ yóò gba ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé, wọ́n fetí sí tí àwọn tí ó ń ṣe oṣó tàbí ṣe àyẹ̀wò Ṣùgbọ́n, ní ti ìwọ, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò fi àyè gbà ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé wòlíì kan dìde gẹ́gẹ́ bí èmi láàrin àwọn arákùnrin rẹ Tìrẹ ni kí o gbọ́ Nítorí èyí ni ohun tí ìwọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Hórébù ní ọjọ́ àjọ, nígbà tí ìwọ wí pé, Kí àwa má ṣe gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run wa tàbí rí iná ńlá yìí mọ́ Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò kú Olúwa sì wí fún mi pé, Ohun tí wọ́n sọ dára Èmi yóò gbé wòlíì kan dìde fún wọn láàrin àwọn arákùnrin wọn bí ìwọ, Èmi yóò fi ọ̀rọ̀ mi sí i ní ẹnu, yóò sì sọ fún wọn gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi tí wòlíì náà yóò sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra à mi yóò sì béèrè lọ́wọ́ ọ rẹ̀ Ṣùgbọ́n bí wòlíì kan bá kùgbù sọ ọ̀rọ̀ kan tí èmi kò paláṣẹ fún un láti sọ ni orúkọ ọ mi tàbí wòlíì tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ ọlọ́run mìíràn, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ ní láti kú Ṣùgbọ́n ìwọ lè wí ní ọkàn rẹ pé, Báwo ni àwa yóò ṣe mọ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run kò sọ Nígbà tí ohun tí wòlíì bá sọ ní orúkọ Olúwa kò bá wá sí ìmúṣẹ tàbí jẹ́ òtítọ́, ìyẹn ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa kò sọ, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ tí sọ láìwádìí Kí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ Ẹlẹ́rìí Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá ti pa àwọn orílẹ̀ èdè tí yóò fi ilẹ̀ wọn fún ọ run, àti nígbà tí ìwọ bá ti lé wọn jáde tí o sì dó sí àwọn ilẹ̀ àti ilé wọn gbogbo Ìwọ yóò ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara à rẹ láàrin ilẹ̀ rẹ tí Olúwa Ọlọ́run fún ọ láti ni Ṣe àwọn ọ̀nà sí wọn àti kí o pín ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún sí ọ̀nà mẹ́ta nítorí kí apànìyàn lè sá níbẹ̀ Èyí ni òfin nípa ẹni tí ó pa ẹlòmíràn tí ó sì sá ṣíbẹ̀ láti pa ẹ̀mí rẹ̀ mọ́ Ẹni tí ó pa aládùúgbò láìmọ̀ọ́mọ̀ṣeé láì jẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́ Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan lè lọ sínú igbó pẹ̀lú aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó sì ti gbé àáké e rẹ̀ láti gé igi náà lulẹ̀, bí àáké náà bá yọ tí ó sì bà aládùúgbò rẹ̀, tí òun sì kú Ọkùnrin yìí lè sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú yìí láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lè máa lépa rẹ̀ nínú ìbínú, kí ó sì lée bá nítorí pé ọ̀nà jìn, kí ó sì paá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ sí ikú, nígbà tí ó ṣeé sí aládùúgbò rẹ̀ láì jẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́ Ìdí nìyìí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara rẹ Tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì fẹ́ agbègbè rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba ńlá a yín, tí ó sì fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí fún wọn, nítorí tí ìwọ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo òfin yìí tí mo pa láṣẹ fún ọ lónìí yìí, kí o fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì rìn ní ọ̀nà an rẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà, kí o ya ìlú mẹ́ta ṣọ́tọ̀ Ṣe èyí kí a má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ni ilẹ̀ rẹ, èyí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, kí ìwọ kí ó má bàá jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títa Ṣùgbọ́n tí ọkùnrin kan bá kórìíra arákùnrin rẹ̀, tí ó sì lúgọ dè é, tí ó mú u tí o lù ú pa, tí ọkùnrin náà sì sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, àwọn olórí ìlú rẹ yóò sì ránṣẹ́ pè é ìwọ, yóò sì mú un padà láti ìlú náà, wọn yóò sì fi í lé àwọn agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ kí ó lè kú Má ṣe ṣàánú fún un O ní láti fọ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò ni Isírẹ́lì, kí ó báà lè dára fún ọ Má ṣe pa òkúta ààlà aládúgbò rẹ dà tí aṣíwájú rẹ fi lélẹ̀ nínú ogún tí ó gbà nínú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ni ní ìní Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo kò tó láti dájọ́ ọkùnrin kan tí o fi ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yóò wù kí ó lè ṣẹ̀ lẹ́bi A ó fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ láti orí ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta Tí alárankàn ẹlẹ́rìí èké bá dúró láti fi ẹ̀ṣùn ẹ̀ṣẹ̀ kan ọkùnrin kan, àwọn méjèèjì tí àríyànjiyàn wà láàrin wọn gbọdọ̀ dúró níwájú Olúwa níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní ìgbà náà Àwọn adájọ́ gbọ́dọ̀ ṣe ìwádìí fínnífínní bí ẹ̀rí bá sì jẹ́ irọ́, tí ó fi ẹ̀rí èké sun arákùnrin rẹ̀, nígbà náà ni kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe sí arákùnrin rẹ̀ O ní láti wẹ búburú kúrò láàrin rẹ Àwọn ènìyàn tókù yóò gbọ́ nípa èyí, wọn yóò sì bẹ̀rù, kí irú nǹkan búburú bẹ́ẹ̀ máa tún sẹ̀ mọ́ láàrin yín Má ṣe fi àánú hàn, ẹ̀mí fún ẹ̀mi, ojú fún ojú, eyín fún eyín, apá fún apá, ẹṣẹ̀ fún ẹṣẹ̀ Ìrìn Àrè Ní Ihà Nígbà náà ni a yípadà, tí a sì mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ sí ihà, a gba ọ̀nà òkun pupa, bí Olúwa ti darí mi Ìgbà pípẹ́ ni a fi ń rìn kiri yíká agbègbè àwọn ìlú olókè Séírì Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, Ẹ ti rìn yí agbégbé ilẹ̀ olókè yìí pẹ́ tó, nísinsin yìí, ẹ yípadà sí ìhà àríwá Fún àwọn ènìyàn náà ní àwọn òfin wọ̀nyí Ẹ ti fẹ́ la ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín kọjá, àwọn ọmọ Ísọ̀ àwọn ará Édómù tí ń gbé ní Séírì Ẹ̀rù yín yóò bà wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi Ẹ má ṣe wá wọn níjà torí pé èmi kò ní fún un yín ní èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn Bí o ti wù kí ó kéré mọ èmi kò ní fún un yín Mo ti fi ilẹ̀ òkè Séírì fún Ísọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀ Ẹ san owó oúnjẹ tí ẹ bá jẹ fún wọn àti omi tí ẹ bá mu   Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ yín Ó ti mójú tó ìrìnàjò yín nínú ihà ńlá yìí Olúwa Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú u yín ní ogojì ọdún wọ̀nyí, débi pé ẹ̀yin kò ṣaláìní ohunkóhun Bẹ́ẹ̀ ni a kọjá ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa, àwọn ọmọ Ísọ̀ tí ń gbé ní Séírì A yà kúrò ní ọ̀nà aginjù èyí tí ó wá láti Élátì àti Ésíóni-Gébérì, a sì rìn gba ọ̀nà ihà Móábù Olúwa sì sọ fún mi pé, Ẹ má ṣe dẹ́rùba àwọn ará Móábù bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe bá wọn jagun torí pé n kò ní fi èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn fún un yín Mo ti fi Árì fún àwọn ọmọ Lọ́tì bí i ìní Àwọn Émímù ti gbé ibẹ̀ rí Àwọn ènìyàn tó sígbọnlẹ̀ tó sì pọ̀, wọ́n ga bí àwọn Ánákì Gẹ́gẹ́ bí Ánákì àwọn ènìyàn náà pè wọ́n ní ará Ráfátì ṣùgbọ́n àwọn ará Móábù pè wọ́n ní Émímù Àwọn ará Hórì gbé ní Séírì kí àwọn ọmọ Ísọ̀ tó lé wọn kúrò níwájú wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ṣe ní ilẹ̀ tí Olúwa yóò fún wọn ní ìní wọn Olúwa sì wí pé, Ẹ dìde, kí ẹ sì la àfonífojì Sérádì kọjá Bẹ́ẹ̀ ni a la àfonífojì náà kọjá Ó gbà wá ní ọdún méjìdínlógójì kí ó tó di wí pé a la àfonífojì Sérédì kọjá láti ìgbà tí a ti kúrò ní Kadesi Báníyà Nígbà náà gbogbo ìran àwọn tí ó jẹ́ jagunjagun láàrin àwọn ènìyàn náà ti ṣègbé kúrò láàrin àwọn ènìyàn náà ní àsìkò yìí bí Olúwa ti búra fún wọn Ọwọ́ Olúwa sì wà lára wọn fún ibi títí gbogbo wọn fi run tan nínú ibùdó Lẹ́yìn tí ẹni tí ó gbẹ̀yìn pátapáta nínú àwọn jagunjagun àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti kú, Olúwa sọ fún mi pé, Lónìí ni ẹ̀yin yóò la agbégbé Móábù kọjá ní Árì Bí ẹ bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Ámónì, ẹ má ṣe halẹ̀ mọ́ wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ bá wọn jagun, torí pé èmi kì yóò fi àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ará Ámónì fún un yín ní ìní Mo ti fi fún àwọn ọmọ Lọ́tì ní ìní Ẹ gbáradì, kí ẹ sì kọjá odò Ánónì Kíyèsi, Mo ti fi Ṣíhónì ará Ámórì, ọba Héṣíbónì àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́ Ẹ bá ilẹ̀ náà jagun kí ẹ sì gbà á Èmi bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìbẹ̀rù àti ìfòyà yín sára gbogbo orílẹ̀ èdè lábẹ́ ọ̀run láti òní lọ Wọn yóò gbọ́ ìròyìn in yín, wọn yóò sì wárìrì, wọn yóò sì wà nínú ìdàmú ọkàn torí i ti yín Mo rán àwọn ìránṣẹ́ sí Síhónì láti ihà Kédémótì pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àlàáfíà wí pé, Jẹ́ kí a la ilẹ̀ ẹ yín kọjá Àwa yóò gba ti òpópónà nìkan A ko ní yà sọ́tùn-ún tàbí sósì Ẹ ta oúnjẹ tí a ó jẹ àti omi tí a ó mu fún wa ní iye owó wọn Kìkì kí ẹ sáà jẹ́ kí a rìn kọjá gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Éṣáù tí ó ń gbé ní Séírì àti àwọn ará Móábù tí ó ń gbé ní Árì, ti gbà wá láàyè títí a fi la Jọ́dánì já dé ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò fún wa Ṣùgbọ́n Ṣíhónì ọba Héṣíbónì kò gbà fún wa láti kọjá Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti mú ọkàn rẹ̀ yigbì, àyà rẹ̀ sì kún fún agídí kí ó ba à le fi lé e yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe báyìí Olúwa sì bá mi sọ̀rọ̀ pé, Kíyèsí i, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi Síhónì àti ilẹ̀ rẹ̀ lé e yín lọ́wọ́ Báyìí, ẹ máa ṣẹ́gun rẹ̀, kí ẹ sì gba ilẹ̀ rẹ̀ Nígbà tí Síhónì àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde wá láti bá wa jagun ní Jáhásì, Olúwa Ọlọ́run wa fi lé wa lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni a ṣẹ́gun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ológun rẹ̀ Nígbà náà, gbogbo ìlú wọn ni a kó tí a sì pa wọ́n run pátapáta tọkùnrin, tobìnrin àti gbogbo ọmọ wọn A kò sì dá ẹnikẹ́ni sí Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú tí a ṣẹ́gun fún ara wa Láti Áróérì, létí odò Ánónì àti láti àwọn ìlú tí ó wà lẹ́bàá odò náà títí ó fi dé Gílíádì, kò sí ìlú tí ó lágbára jù fún wa, Olúwa Ọlọ́run wa fi gbogbo wọn fún wa Ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa Ọlọ́run wa, ẹ kò súnmọ́ ọ̀kan nínú ilẹ̀ àwọn ará Ámónì, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dé ilẹ̀ tí ó lọ sí Jábókù, tàbí ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú òkè e nì ká Lílọ Sí Ogun Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀ta rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì, yóò wà pẹ̀lú rẹ Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá ṣíwájú, yóò sì bá ọmọ ogun sọ̀rọ̀, yóò sì wí pé, Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀ta rẹ Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi àyè fún ìjayà níwájú u wọn Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ni ẹni tí ó ń lọ pẹ̀lú rẹ láti jà fún ọ kí ó sì fún ọ ní ìṣẹgun Àwọn olórí ogun yóò sì wí fún àwọn ènìyàn pé, Ẹnikẹ́ni tí ó kọ́ ilé túntún tí kò sì tì ì yà á sọ́tọ̀ Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí ó lè kú ṣójú ogun kí elòmìíràn sì gbà á Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó gbin ọgbà àjàrà kan tí kò sì tí ì bẹ̀rẹ̀ sí ń gbádùn rẹ̀ Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmìíràn sì gbádùn rẹ̀ Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wá ògo obìnrin kan tí kò ì tí ì fẹẹ Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì fẹẹ́ Nígbà náà ni olórí yóò tún fi kún un pé Ǹjẹ́ ọkùnrin kankan ń bẹ̀rù tàbí páyà Jẹ́ kí ó lọ ilé nítorí kí arákùnrin rẹ̀ má baà wá tún dáyà fò ó Nígbà tí olórí ogun bá ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn, wọn yóò yan olórí ogun lórí i rẹ̀ Nígbà tí ó bá sún mọ́ iwájú láti dojú kọ ìlú kan láti bá a jà, nígbà náà ni kí ó fi àlàáfíà lọ̀ ọ́ Tí wọ́n bá gbà tí wọ́n sì sí ìlẹ̀kùn, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ yóò máa jẹ́ olùsìn fún ọ, wọn ó sì máa sìn ọ́ Tí wọ́n bá kọ̀ láti bá ọ ṣe àlàáfíà ṣùgbọ́n tí wọ́n bá gbógun tì ọ́, nígbà náà ni kí ìwọ gbà á Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá fi lé ọ lọ́wọ́, ẹ pa gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà níbẹ̀ Ní ti obìnrin, àwọn ọmọdé, ohun ọ̀sìn àti gbogbo ohun tí ó kù nínú ìlú náà, o lè mú ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìkógún fún ara rẹ O sì lè lo ìkógún tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ta rẹ Báyìí ni ìwọ yóò ṣe sí gbogbo ìlú tí wọ́n wà ní ọ̀nà jínjìn sí ọ tí wọn kò sì tara àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ rẹ Ṣùgbọ́n, nínú àwọn ìlú ti àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, má ṣe dá ohun ẹlẹ́mìí kankan sí Pa wọ́n run pátapáta, àwọn ọmọ Hítì, ọmọ Ámórì, ọmọ Kénánì, ọmọ Pérísì, ọmọ Hífì, ọmọ Jébúsì gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pa á láṣẹ fún ọ Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kọ́ ọ láti tẹ̀lé gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe nínú sísin àwọn ọlọ́run wọn, ìwọ yóò sì sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ Nígbà tí o bá dóti ìlú kan láti ọjọ́ pípẹ́, ẹ bá wọn jà láti gbà á, má ṣe pa àwọn igi ibẹ̀ run nípa gbígbé àáké lé wọn, nítorí o lè jẹ èso wọn Má se gé wọn lulẹ̀ Nítorí igi ìgbẹ́ ha á ṣe ènìyàn bí, tí ìwọ ó máa dọ̀tí rẹ̀ Ṣùgbọ́n o lè gé àwọn igi tí o mọ̀ pé wọn kì í ṣe igi eléṣo lulẹ̀ kí o sì lò wọ́n láti kọ́ ìṣọ́ sí ìlú tí ó ń bá ọ jagun, títí tí yóò fi ṣubú Ìdáríjì Ìpànìyàn Láìnítumọ̀ Tí a bá rí ọkùnrin tí a pa, ní ìdùbúlẹ̀ ní pápá nínú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ láti jogún, tí a kò sì mọ ẹni tí ó pa á, àwọn àgbààgbà yín yóò jáde lọ láti wọn jíjìnnà ibi òkú sí ìlú tí ó wà nítòòsí Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà ìlú tí ó wà nítòòsí òkú yóò mú ẹgbọ̀rọ̀ abo màlúù tí kò ì siṣẹ́ àti tí kò ì tíì fà sí àmì ìsìn ẹrú, kí wọn sìn ín wá sí àfonífojì tí a kò ì tíì ro tàbí gbìn àti ibi tí odò ṣíṣàn wà Níbẹ̀ ní àfonífojì wọn yóò kán ọrùn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù Àwọn àlùfáà, ọmọ Léfì yóò wá ṣíwájú, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti bùkún ní orúkọ Olúwa àti láti parí gbogbo ẹjọ́ àríyànjiyàn àti ọ̀rọ̀ ìlú Nígbà náà ni gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú tí ó wà nítòsí yóò wẹ ọwọ́ wọn lórí ẹgbọrọ abo màlúù tí a ti kan ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì, wọn yóò sì sọ pé, ọwọ́ wa kò ta ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, tàbí kí ojú wa rí i ní títa sílẹ̀ Dáríjìn, Olúwa , àwọn ènìyàn rẹ ni Ísírẹ́lì, tí ìwọ ti dá sílẹ̀, àti kí ìwọ má ṣe gba ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìsẹ̀ ní àárin àwọn ènìyàn rẹ ní Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n kí a dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yìí jìn Nígbà náà ni ìwọ wẹ̀ kúró láàrin rẹ ẹ̀bi títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó tọ́ níwájú Olúwa Nígbà tí o bá lọ sí ogun sí àwọn ọ̀ta rẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ tí o sì mú àwọn ìgbékùn, tí o sì rí obìnrin tí ó dára lára àwọn ìgbékùn, tí o sì ní ìfẹ́ síi, o lè mu u gẹ́gẹ́ bí aya à rẹ Mú u wá sí ilé e rẹ kí o sì jẹ́ kí ó fá irun orí i rẹ̀, gé èékánná an rẹ̀, kí o sì mú aṣọ tí ó wọ̀ nígbà tí ó di ìgbékùn sí ẹ̀gbẹ́ kan Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ń gbé ilé rẹ tí ó sì ti sọ̀fọ̀ baba àti ìyá rẹ̀ fún odidi osù kan, nígbà náà ni o lè tọ̀ ọ́ lọ kí o sì ṣe ọkọ rẹ̀ kí ó jẹ́ aya rẹ Bí inú rẹ̀ kò bá sì dùn si i, jẹ́ kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá fẹ́ O kò gbọdọ̀ tà á tàbí lò ó bí ẹrú, lẹ́yìn ìgbà tí o ti dójú tì í Bí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, tí ó sì fẹ́ ọ̀kan ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ èkejì, tí àwọn méjèèjì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un ṣùgbọ́n tí àkọ́bí jẹ́ ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn Nígbà tí ó bá ń pín ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ àkọ́bí fún ọmọ ìyàwó tí kò fẹ́ràn Ó ní láti fi ipò ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn fun un gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí i rẹ̀ nípa fífún un ní ìlọ́po ìpín gbogbo ohun tí ó ní Ọmọ yẹn ni àmì àkọ́kọ́ agbára baba rẹ̀ Ẹ̀tọ́ àkọ́bí jẹ́ tirẹ̀ Bí ọkùnrin kan bá ní aláìgbọ́ràn tàbí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tí kò gbọ́rọ̀ sí baba àti ìyá rẹ̀ tí kò sì ní í gbà tí wọ́n bá ń bá a wí, baba àti ìyá rẹ̀ yóò gbá a mú, wọn yóò mu wá fún àwọn àgbààgbà ní ẹnu bodè ìlú u rẹ̀ Wọn yóò sì wí fún àwọn àgbààgbà pé, Ọmọ wa yìí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ Kò ní gbọ́rọ̀ sí wa Ó jẹ́ oníwà búburú àti ọ̀mùtí-para Nígbà náà ni gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò sọ ọ́ ní òkúta pa Ìwọ yóò sì mú ìwà ibi kúrò láàrin yín, gbogbo Ísírẹ́lì yóò gbọ́ ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n Bí ọkùnrin kan tí ó jẹ̀bi ẹ̀sùn bá ní láti kú tí ó sì kú, tí a sì gbé òkú rẹ̀ kọ́ sára igi, o kò gbọdọ̀ fi òkú rẹ̀ sílẹ̀ sára igi ní gbogbo òru Gbìyànjú láti sin ín ní ọjọ́ náà gan an, nítorí ẹni tí a bá gbékọ́ sórí igi wà lábẹ́ ègún Ọlọ́run O kò gbọdọ̀ ba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún jẹ́ Ìrúfin Ìgbéyàwó Bí o bá rí màlúù tàbí àgùntàn arákùnrin rẹ tí ó ń sọnù, má ṣe ṣé àìkíyèsí i rẹ̀ ṣùgbọ́n rí i dájú pé o mú padà wá fún un Bí ọkùnrin náà kì í bá gbé ní tòsí rẹ tàbí bí o kò bá mọ ẹni náà, mú un lọ ilé pẹ̀lú rẹ kí o sì fi pamọ́ títí yóò fi wá a wá Nígbà náà ni kí o fi fún un Ṣe bákan náà tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ arákùnrin rẹ tàbí aṣọ ìlekè tàbí ohunkóhun rẹ̀ tí ó sọnù Má ṣe ṣe àìkíyèsí i rẹ̀ Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù arákùnrin rẹ tí o dùbúlẹ̀ sójú ọ̀nà, má ṣe ṣàìfiyèsí i rẹ̀, ràn án lọ́wọ́ láti dìde dúró lórí ẹṣẹ̀ rẹ̀ Obìnrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, tàbí kí ọkùnrin wọ aṣọ obìnrin, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó ṣe èyí Bí o bá se alábàápàdé ìtẹ́ ẹyẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, bóyá lára igi tàbí lórí ilẹ̀, tí ìyá wọn sì jòkòó lórí àwọn ọmọ, tàbí lórí àwọn ẹyin, má ṣe gbé ìyá pẹ̀lú àwọn ọmọ O lè gbé ọmọ, ṣùgbọ́n rí i dájú pé o jọ̀wọ́ ìyá lọ́wọ́ lọ, kí ó baà lè dára fún ọ àti kí o lè ní ẹ̀mí gígùn Nígbà tí o bá kọ́ ilé túntún, mọ odi yí òrùlé rẹ̀ ká nítorí kí o má baà mú ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ wá sórí ilẹ̀ rẹ bí ẹnikẹ́ni bá ṣubú láti òrùlé Má ṣe gbin oríṣìí èso méjì sínú ọgbà àjàrà rẹ bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe èṣo oko tí o gbìn nìkan ṣùgbọ́n èṣo ọgbà àjàrà pẹ̀lú yóò bàjẹ́ Má ṣe fi akọ màlúù àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tulẹ̀ pọ̀ Má ṣe wọ aṣọ onírun àgùntàn àti aṣọ funfun papọ̀ Kí o ṣe wajawaja sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aṣọ ìlẹ̀kẹ̀ rẹ Bí ọkùnrin kan bá mú ìyàwó àti, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, kórìíra rẹ̀, tí o sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sì i tí o sì fún un ní orúkọ búburú, wí pé, Mo fẹ́ obìnrin yìí, ṣùgbọ́n nígbà tí mo sún mọ́ ọn Èmi kò rí àmì ìbálé e rẹ̀ Nígbà náà ni baba ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ yóò mú ẹ̀rí pé ó ti wà ní ìbálé tẹ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà ìlú ní ẹnu bodè Baba obìnrin náà yóò wí fún àwọn àgbààgbà, pé Mo fi ọmọbìnrin mi fún ọkùnrin yìí láti fẹ́ níyàwó, ṣùgbọ́n ó kórìíra rẹ̀ Ní ìsinsin yìí ó ti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí i ó sì wí pé, Èmi kò rí ọmọbìnrin rẹ kí ó wà ní wúndíá Ṣùgbọ́n níhìn-ín yìí ni ẹ̀rí ìbálé ọmọbìnrin mi Nígbà náà ni àwọn òbí rẹ̀ yóò fí aṣọ hàn níwájú àwọn àgbààgbà ìlú, àwọn àgbààgbà yóò sì mú ọkùnrin náà, wọn yóò sì jẹ́ ẹ́ níyà Wọn yóò sì gba ìtanràn ọgọ́rùn ún ṣékélì owó fàdákà fún baba ọmọbìnrin náà, nítorí ọkùnrin yìí ti fi orúkọ búburú fún wúndíá Ísírẹ́lì Yóò sì máa ṣe ìyàwó rẹ̀ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ayé e rẹ̀ Ṣùgbọ́n bí ẹ̀sùn náà bá jẹ́ òtítọ́ tí a kò sí rí ẹ̀rí ìbálé obìnrin náà, wọn yóò mú wá sí ẹnu ọ̀nà ilé baba rẹ̀ níbẹ̀ sì ni àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò ti sọ ọ́ ní òkúta pa Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Isírẹ́lì nípa ṣíṣe aṣẹ́wó nígbà tí ó wà nílé baba rẹ̀ Ẹ ní láti pọ ohun búburú kúrò láàrin yín Bí o bá rí ọkùnrin kan tí ó bá ìyàwó ọkùnrin mìíràn lòpọ̀, àwọn méjèèjì ní láti kú Ẹ ní láti pọ ohun búburú kúrò láàrin Ísírẹ́lì Bí ó bá ṣẹlẹ̀ wí pé ọkùnrin kan pàde wúndíá tí a ti fi fún ni láti fẹ́ láàrin ìlú tí ó sì lòpọ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, ìwọ yóò mú àwọn méjèèjì lọ sí ẹnu ibodè ìlú náà kí o sì sọ wọ́n ní ókúta pa nítorí ọmọbìnrin náà wà ní ìlú kò sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àti ọkùnrin náà nítorí ó ba ìyàwó ọkùnrin mìíràn jẹ́ O ní láti wẹ búburú kúrò láàrin rẹ Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìgbẹ́ ní ó ti ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrín kan ti pàde ọmọbìnrin tí a ti fẹ́ sọ́nà tí o sì fi tagbára tagbára bá a se, ọkùnrin náà nìkan tí ó se èyí ni yóò kú Má se fi ohunkóhun ṣe ọmọbìnrin náà kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tọ́ sí ikú Ẹjọ́ yìí rí bí i ti ẹnìkan tí a gbámú tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ Nítorí ọkùnrin náà rí ọmọbìnrin náà ní ìta ibodè, bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin àfẹ́sọ́nà kígbe, kò sí ẹnìkankan níbẹ̀ láti gbà á kalẹ̀ Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin pàde wúndíá tí kò ì tí ì ní àfẹ́sọ́nà tí ó sì fi tipátipá báa ṣe tí a gbá wọn mú Ó ní láti san àádọ́ta fàdákà fún baba obìnrin náà, nítorí tí ó ti bà á jẹ́ Kò lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó sì wà láàyè Ọkùnrin kò gbọdọ̀ fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀ kò gbọdọ̀ sọ ìtẹ́ baba rẹ̀ di àìlọ́wọ̀ Ìwà àìmọ́ nínú àgọ́ Kí ẹnikẹ́ni tí a fọ́ ní kóró ẹpọ̀n nípa rírùn tàbí gígé má ṣe wọ inú ìjọ ènìyàn wá Kí ọmọ àlè má ṣe wọ ìpéjọ Olúwa , pàápàá títí dé ìran kẹwàá Kí Ámónì tàbí Móábù tàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ wọn má ṣe wọ ìpéjọ Olúwa , pàápàá títí dé ìran kẹ̀wàá Nítorí wọn kò fi àkàrà àti omi pàdé e yín lójú ọ̀nà nígbà tí ò ń bọ̀ láti Éjíbítì àti nítorí wọ́n gba ẹ̀yà iṣẹ́ láti fi ọ́ gégún Bálámù ọmọ Béórì ará a Pétórì ti Árámù Náháráímù Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò ní fetí sí Bálámù ṣùgbọ́n ó yí ègún sí ìbùkún fún ọ, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ fẹ́ràn rẹ Má ṣe wá ìpinnu ìbádọ́rẹ́ pẹ̀lú u wọn níwọ̀n ìgbà tí o sì wà láàyè Má ṣe kórìíra ará Édómù kan nítorí arákùnrin rẹ ni Má se kórìíra ará Éjíbítì, nítorí o gbé gẹ́gẹ́ bí àléjò ní ilẹ̀ rẹ̀ Ìran kẹta àwọn ọmọ tí a bí fún wọn lè wọ ìpéjọ Olúwa Nígbà tí o bá dó ti àwọn ọ̀ta rẹ, pa gbogbo ohun àìmọ́ kúrò Bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin rẹ bá jẹ́ aláìmọ́ nítorí ìtújáde tí ó ní, o ní láti jáde kúrò nínú àgọ́, kí o má ṣe wọ inú àgọ́ Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ o ní láti wẹ ara rẹ, àti ní àṣálẹ́ kí o padà sínú àgọ́ Sàmì sí ibìkan lóde àgọ́, níbi tí o lè máa lọ láti dẹ ara rẹ lára Ìwọ yóò mú igi pẹ̀lú ohun ìjà rẹ àti nígbà tí o bá dẹ ara rẹ lára tán, gbẹ́ kòtò kí o sì bo ìgbẹ́ rẹ Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrin àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀taà rẹ lé ọ lọ́wọ́ Àgọ́ ọ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrin yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ ọ yín Bí ẹrú kan bá ti gba ààbò lọ́dọ̀ rẹ, má ṣe fi lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́ Jẹ́ kí ó máa gbé láàrin rẹ níbikíbi tí ó bá fẹ́ àti èyíkéyí ìlú tí ó bá mú Má se ni í lára Kí ọkùnrin tàbí obìnrin Ísírẹ́lì má ṣe padà di alágbérè ojúbọ òrìṣà O kò gbọdọ̀ mú owó iṣẹ́ panṣágà obìnrin tàbí ọkùnrin wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́ kankan nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ korìíra àwọn méjèèjì Má ṣe ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá O lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní Bí o bá jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ ọ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ Ṣùgbọ́n tí o bá fà ṣẹ́yìn láti jẹ́ ẹ̀jẹ́, o kò ní jẹ̀bi Rí i dájú pé o ṣe ohunkóhun tí o bá sọ jáde láti ẹnu rẹ, nítorí pé o jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú ẹnu ara rẹ Bí o bá wọ inú ọgbà àjàrà aládùúgbò rẹ, o lè jẹ gbogbo èso àjàrà tí o bá fẹ́, ṣùgbọ́n má ṣe fi ìkankan sínú agbọ̀n rẹ Bí o bá wọ inú oko ọkà aládùúgbò rẹ, o lè fi ọwọ́ rẹ ya sírì rẹ̀, ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ki dòjé bọ ọkà tí ó dúró Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ obìnrin kan ní ìyàwó tí ó wá padà bà á nínú jẹ́ nítorí ó rí ohun àìtọ́ kan nípa rẹ̀, tí ó sì kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ si i, fi fún un kí ó sì lọ jáde kúrò ní ilé è rẹ, tí ó bá di ìyàwó ọkùnrin mìíràn lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò nílé rẹ, àti tí ọkọ rẹ̀ kejì kò bá fẹ́ràn rẹ̀ tí ó sì kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ sí i, kí ó fi fún un kí ó sì lé e kúrò nílé e rẹ̀, tàbí tí ọkọ rẹ̀ kejì bá kú, nígbà náà ni ọkọ, tí ó ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò gbọdọ̀ fẹ ẹ mọ́ lẹ́yìn tí ó ti di àìmọ́ Nítorí èyí ni ìríra níwájú Olúwa Má ṣe mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sórí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún Bí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, o kò gbọdọ̀ ran lọ sí ogun tàbí kí ó ní iṣẹ́ kan láti ṣe Ó ní láti ní òmìnira fún ọdún kan kí ó dúró sílé kí ó sì mú inú dídùn bá ìyàwó rẹ̀ tí ó fẹ́ Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ìyá ọlọ tàbí ọmọ ọlọ ní ògo, nítorí pé ẹ̀mí ènìyàn ni ó gbà ní ògo n nì Bí a bá mú ọkùnrin kan tí ó jí ọ̀kan nínú arákùnrin rẹ̀ ní Ísírẹ́lì gbé àti tí ó jí ọ̀kan nínú ẹrú tàbí kí ó tàá, ẹni tí ó jí ènìyàn gbé ní láti kú Ẹní láti wẹ búburú kúrò láàrin yín Ní ti àrùn ẹ̀tẹ̀ kíyèsára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì ti pàṣẹ fún ọ O ní láti máa fi ìṣọ́ra tẹ̀lé ohun tí mo ti pa láṣẹ fún wọn Rántí ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ṣe sí Míríámù lójú ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí o jáde kúrò ní Éjíbítì Nígbà tí o bá wín arákùnrin rẹ ní ohunkóhun, má ṣe lọ sí ilé rẹ̀ láti gba ohun tí ó bá mú wá bí ẹ̀rí Dúró síta gbangba kí o sì jẹ́ kí ọkùnrin tí o wín mú ògò rẹ jáde wá fún ọ Bí ọkùnrin náà bá jẹ́ talákà má ṣe lọ sùn ti ìwọ ti ògo rẹ Dá aṣọ ìlékè rẹ padà ní àṣálẹ́ kí ó báà le sùn lórí i rẹ̀ Nígbà náà ni yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, ó sì má a jásí ìwà òdodo níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ Má ṣe ni alágbàṣe kan lára tí ó jẹ́ talákà àti aláìní, bóyá ó jẹ́ arákùnrin Isírẹ́lì tàbí àlejò tí ó ń gbé ní ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ San owó iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà kí ó tó di àṣàálẹ́, nítorí ó jẹ́ talákà, ó sì gbẹ́kẹ̀lé e bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ó lè képe Olúwa sí ọ, o sì máa gba ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ Baba kò gbọdọ̀ kú fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí àwọn ọmọ kú fún bàbá wọ́n olúkúlùkù ní láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀ Má ṣe yí ìdájọ́ po fún àlejò tàbí aláìní baba, tàbí gba aṣọ ìlékè opó bí ẹ̀rí Rántí pé o jẹ́ ẹrú ní Éjíbítì tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì gbà ọ́ níbẹ̀ Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ Nígbà tí o bá ń gun igi ólífì lára àwọn igi i rẹ, má ṣe padà lọ sí ẹ̀ka náà ní ìgbà kejì Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó Nígbà tí o bá kórè èṣo àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́ Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó Rántí pé o ti jẹ́ àlejò ní Éjíbítì Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí Nígbà tí àwọn ènìyàn méjì bá ń jà, kí wọn kó ẹjọ́ lọ sí ilé ìdájọ́, kí àwọn onídàájọ́ dá ẹjọ́ náà, kí wọn dá àre fún aláre àti ẹ̀bi fún ẹlẹ́bi Bí ó bá tọ́ láti na ẹlẹ́bi, kí onídàájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀ kí a sì nà án ní ojú u rẹ̀ ní iye pàsán tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀ Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàsán lọ Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀ Má ṣe di akọ màlúù lẹ́nu nígbà tí o bá ń pa ọkà Bí àwọn arákùnrin rẹ bá jọ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan wọn sì kú láìní ọmọkùnrin, opó rẹ̀ kò gbọdọ̀ fẹ́ ọkọ mìíràn tayọ ẹbí ọkọ rẹ̀ Arákùnrin ọkọ rẹ̀ ni yóò mú u ṣe aya, òun ni yóò sì ṣe ojúṣe ọkọ fún un Ọmọkùnrin tí ó bá kọ́ bí ni yóò máa jẹ́ orúkọ arákùnrin rẹ̀ tí ó kú náà, kí orúkọ rẹ̀ má baá parẹ́ ní Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ fi aya arákùnrin rẹ̀ ṣe aya rẹ̀, obìnrin náà yóò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà ní ẹnu bodè ìlú láti sọ pé, Arákùnrin ọkọ ọ̀ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arákùnrin rẹ̀ ró ní Ísírẹ́lì Kò ní ṣe ojúṣe rẹ̀ bí arákùnrin ọkọ mi sí mi Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ yóò pè é, wọn yóò sì bá sọ̀rọ̀ Bí ó bá sì kọ̀ jálẹ̀ tí ó bá sọ pé, Èmi kò fẹ́ láti fẹ́ ẹ, opó arákùnrin rẹ̀ yìí yóò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ojú àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀, yóò yọ bàtà ẹṣẹ̀ rẹ̀ kan, yóò sì tu itọ́ sí ọkùnrin náà lójú, yóò sì wí pé, Èyí ni ohun tí a ṣe sí ọkùnrin tí kò jẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ wà títí ayé A ó sì mọ ìdílé arákùnrin yìí ní Isírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Ìdílé tí a yọ bàtà rẹ̀ Bí ọkùnrin méjì bá ń jà, tí ìyàwó ọ̀kan nínú wọn bá sì wá láti gbéjà ọkọ rẹ̀ kúró lọ́wọ́ ọkùnrin tí ń lù ú, tí ó sì nawọ́ di nǹkan ọkùnrin abẹ́ ẹ rẹ̀ mú Ìwọ yóò gé ọwọ́ rẹ̀ náà kúrò Má ṣe sàánú fún un Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ ọ̀kan wíwo àti ọ̀kan fífúyẹ́ Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òsùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ Nítorí Olúwa Ọlọ́run kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí, àní ẹnikẹ́ni tí ń ṣe àìṣòdodo Rántí ohun tí àwọn ará Ámélékì ṣe sí i yín ní ọ̀nà nígbà tí ẹ̀ ń jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá Nígbà tí àárẹ̀ mú un yín tí agara sì dá a yín, wọ́n pàdé e yín ní ọ̀nà àjò o yín, wọ́n gé àwọn tí ó rẹ̀yìn kúrò, wọn kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá fún un yín ní ìsinmi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta yín tí ó yí i yín ká ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run ń fi fún yín láti ni ní ìní, ẹ̀yin yóò sì pa ìrántí Ámélékì rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run Má ṣe gbàgbé Àkọ́so Àti Ìdámẹ́wàá Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí ìwọ sì ti jogún, tí o sì ti ń gbé níbẹ̀, mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèṣè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé Mo sọ ọ́ di mímọ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba wa Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Árámíà, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Éjíbítì pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀ èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn Ṣùgbọ́n àwọn ará Éjíbítì ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá níyà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe Nígbà náà ni a kégbe pe Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wa, Olúwa sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa Nígbà náà ni Olúwa mú wa jáde wá láti Éjíbítì pẹ̀lu ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ Olúwa ti fún mi wá Gbé agbọ̀n náà ṣíwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀ Ìwọ àti àwọn ọmọ Léfì àti àjòjì láàrin yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí Olúwa ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ Nígbà tí o bá ṣetán láti ya ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí o ti mú jáde ní ọdún kẹ́ta sọ́tọ̀ sí apákan Ọdún ìdámẹ́wàá, ìwọ yóò fi fún ọmọ Léfì, àjòjì, aláìní baba àti opó, kí wọn kí ó lè jẹ ní àwọn ìlú rẹ, kí wọn sì yó Nígbà náà ní kí o wí fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, Èmi ti mú ohun mímọ́ kúrò nínú ilé mi, èmi sì ti fi fún àwọn Léfì, àwọn àjòjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó, gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tí ìwọ ti pa láṣẹ Èmi kò yípadà kúrò nínú àṣẹ rẹ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbàgbé ọ̀kankan nínú wọn Èmi kò jẹ lára ohun mímọ́ ní ìgbà tí mo ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu nínú wọn ní ìgbà tí mo wà ní àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi nínú wọn fún òkú Èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run mi, èmi sì ti ṣe gbogbo ohun tí ó pa láṣẹ fún mi Wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, ibùgbé mímọ́ rẹ, kí o sì bùkún fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àwọn babańlá wa, ilẹ̀ tí ó ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin Olúwa Ọlọ́run rẹ pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa tẹ̀lé àwọn ìlànà àti òfin, kí o sì máa ṣe wọ́n pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo àyà rẹ Ìwọ jẹ́wọ́ Olúwa ní òní pé Olúwa ni Ọlọ́run rẹ, àti pé ìwọ yóò máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, àti pé ìwọ yóò máa pa ìlànà rẹ̀, àṣẹ rẹ̀ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti pé ìwọ yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí i Ní òní ni Olúwa jẹ́wọ́ rẹ pé ìwọ ni ènìyàn òun, ilé ìṣúra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí, àti pé ìwọ yóò máa pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́ Òun sì jẹ́wọ́ pé, òun yóò gbé ọ sókè ju gbogbo orílẹ̀ èdè tí òun ti dá lọ, ní ìyìn, ní òkìkí àti ní ọlá kí ìwọ kí ó le jẹ́ ènìyàn mímọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí Pẹpẹ Ní Orí Òkè Ébálì Mósè àti àwọn àgbà Isírẹ́lì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé Pa gbogbo àṣẹ tí mo fún ọ lónìí mọ́ Nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì sí inú ilẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, gbékalẹ̀ lára àwọn òkúta ńlá àti aṣọ ìlekè rẹ pẹ̀lú ẹfun Kí o kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí o bá ti ń ré kọjá láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ébálì, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun Kọ́ Pẹpẹ ṣíbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn Kí o kọ́ pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú òkúta nínú pápá kí o sì sun ẹbọ ni orí i rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀ Nígbà náà ni Móṣè àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, sọ fún Ísírẹ́lì pé, Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Ísírẹ́lì, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn Olúwa Ọlọ́run rẹ báyìí Gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí Ní ọjọ́ kan náà Móṣè pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé Nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gérísímù láti ṣúre fún àwọn ènìyàn Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì, Jóṣẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ébálì láti gé ègún Rúbẹ́nì, Gádì, àti Ásérì, àti Ṣébúlúnì, Dánì, àti Náfitanì Àwọn ẹ̀yà Léfì yóò ké sí gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì ní ohùn òkè Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa , iṣẹ́ ọwọ́ onísọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, Àmín! Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójú ti baba tàbí ìyá rẹ̀ Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, Àmín! Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládúgbò o rẹ̀ Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, Àmín! Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó si afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, Àmín! Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àléjò, aláìní baba tàbí opó Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, Àmín! Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀ Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, Àmín! Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbalòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, Àmín! Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá a rẹ̀ Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, Àmín! Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀ Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, Àmín! Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, Àmín! Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, Àmín! Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa síse wọ́n Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, Àmín! Ìbùkún Fún Ìgbọ́ran Bí o bá gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pa láṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀ èdè ayé lọ Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sóríì rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko Ìbùkún ni fún ọmọ inú ù rẹ, àti èṣo ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ìpo ìyẹ̀fun rẹ Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí Ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde Olúwa yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀ta tí ó dìde sí ọ yóò bì subú níwájú rẹ Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje Olúwa yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ ọ rẹ lé Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ Olúwa yóò fi ọ́ múlẹ̀ bí ènìyàn mímọ́, bí ó ti ṣe ìlérí fún ọ lórí ìbúra, bí o bá pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ mọ́ tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀ Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé yóò rí i pé a pè ọ́ ní orúkọ Olúwa , wọn yóò sì bẹ̀rù rẹ Olúwa yóò fi àlàáfíà fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, fún ọmọ inú rẹ, irú ohun ọ̀sìn rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fún ọ Olúwa yóò ṣí ọ̀run sílẹ̀, ìṣúra rere rẹ̀ fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àsìkò rẹ àti láti bùkún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ Ìwọ yóò yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ṣùgbọ́n ìwọ kò ní í yá lọ́wọ́ ẹnìkankan Olúwa yóò fi ọ́ ṣe orí, ìwọ kì yóò sì jẹ́ ìrù Bí o bá fi etí sílẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ tí mo fi fún ọ kí o sì máa rọra tẹ̀lé wọn, ìwọ yóò máa wà lókè, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò wà ní ìsàlẹ̀ láé Má se yà sọ́tùn ún tàbí sósì kúrò, nínú èyíkéyìí àwọn àṣẹ tí mo fi fún ọ ní òní yìí, kí o má ṣe tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti máa sìn wọ́n Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sóríì rẹ yóò sì máa bá ọ lọ Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko Ègún ni fún Agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èṣo ilẹ̀ rẹ, ìbísí màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé ègún sì ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde Olúwa yóò rán ègún sóríì rẹ, rúdurùdu àti ìfibú nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ rẹ lé, títí ìwọ yóò fi parun àti wá sí ìparun lójijì nítorí búburú tí o ti ṣe ní kíkọ̀ mi sílẹ̀ Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-àrùn bá ọ jà títí tí yóò fi pa ọ́ run kúrò ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní Olúwa yóò kọlù ọ́ pẹ̀lú àrùn ìgbẹ́, pẹ̀lú ibà àti àìsàn wíwú, pẹ̀lú ìján ńlá àti idà, pẹ̀lú ìrẹ̀dànù àti imúwòdù tí yóò yọ ọ́ lẹ́nu títí ìwọ yóò fi parun Ojú ọ̀run tí ó wà lórí rẹ yóò jẹ́ idẹ, ilẹ̀ tí ń bẹ níṣàlẹ̀ rẹ yóò sì jẹ́ irin Olúwa yóò yí òjò ilẹ̀ rẹ sí eekuru ẹ̀tù ìbọn yóò sì wá sílẹ̀ láti ojú ọ̀run títí tí yóò fi pa ọ́ run Olúwa yóò fi ọ́ gégùn ún láti ṣubú níwájú àwọn ọ̀ta rẹ Ìwọ yóò tọ̀ wọ́n wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n ìwọ yóò ṣá fún wọn ní ọ̀nà méje, ìwọ yóò sì padà di ohun ìbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba lórí ayé Òkú rẹ yóò jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ayé, àti pé kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóò lé wọn kúrò Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú oówo, Éjíbítì àti pẹ̀lú kókó, ojú egbò kíkẹ̀ àti ìhúnra Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú ìsínwín, ojú fífọ́ àti rúdurùdu àyà Ní ọ̀sán gangan ìwọ yóò fi ọwọ́ talẹ̀ kiri bí ọkùnrin afọ́jú nínú òkùnkùn ìwọ kì yóò ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí o bá ń ṣe, ojoojúmọ́ ni wọn yóò máa ni ọ́ lára àti jà ọ́ ní olè, tí kò sì ní í sí ẹnìkan láti gbà ọ́ Ìwọ yóò gba ògo láti fẹ obìnrin kan ṣùgbọ́n ẹlòmíràn yóò gbà á yóò sì tẹ́ ẹ́ ní ògo Ìwọ yóò kọ́ ilé, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò gbé ibẹ̀ Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kò tilẹ̀ ní gbádùn èṣo rẹ Màlúù rẹ yóò di pípa níwájú ù rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò jẹ ìkankan nínú rẹ̀ Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ yóò sì di mímú pẹ̀lú agbára kúrò lọ́dọ̀ rẹ, a kì yóò sì da padà Àgùntàn rẹ yóò di mímú fún àwọn ọ̀ta rẹ, ẹnìkankan kò sì ní gbà á Àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ yóò di mímú fún àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, ìwọ yóò sì fi ojú ù rẹ sọ́nà dúró dè wọ́n láti ọjọ́ dé ọjọ́, ìwọ yóò sì jẹ́ aláìlágbára láti gbé ọwọ́ Èṣo ilẹ̀ rẹ àti gbogbo iṣẹ́ làálàá rẹ ni orílẹ̀-èdè mìíràn tí ìwọ kò mọ̀ yóò sì jẹ, ìwọ yóò jẹ́ kìkì ẹni ìnilára àti ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀ Ìran tí ojú ù rẹ yóò rí, yóò sọ ọ́ di òmùgọ̀ Olúwa yóò lu eékún àti ẹṣẹ̀ rẹ pẹ̀lú oówo dídùn tí kò le san tán láti àtẹ́lẹṣẹ̀ méjèèjì rẹ lọ sí òkè orí rẹ Olúwa yóò lé ọ àti ọba tí ó yàn lóríì rẹ lọ sí orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀ tàbi ti àwọn baba rẹ kò mọ̀ Ibẹ̀ ni ìwọ̀ yóò sì sin ọlọ́run mìíràn, ọlọ́run igi àti òkúta Ìwọ yóò padà wá di ohun ìbẹ̀rù àti ohun ẹ̀gàn àti ẹlẹ́yà sí gbogbo orílẹ̀ èdè tí Olúwa yóò lé ọ lọ Ìwọ yóò gbin irúgbìn púpọ̀ ṣùgbọ́n ìwọ yóò kórè kékeré, nítorí eṣú yóò jẹ̀ ẹ́ run Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà púpọ́ ìwọ yóò sì ro wọ́n ṣùgbọ́n kò ní mú wáìnì náà tàbí kó àwọn èṣo jọ, nítorí kòkòrò yóò jẹ wọ́n run Ìwọ yóò ní igi ólífì jákèjádò ilẹ̀ rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò ní lo òróró náà, nítorí ólífì náà yóò rẹ̀ dànù Ìwọ yóò ní àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ṣùgbọ́n ìwọ kò ní pa wọ́n mọ́, nítorí wọn yóò lọ sí ìgbèkùn Ọ̀wọ́ eṣú yóò gba gbogbo àwọn igi rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ Àlejò tí ń gbé láàrin rẹ yóò gbé sókè gíga jù ọ́ lọ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò máa di ìrẹ̀sílẹ̀ Yóò yà ọ́, ṣùgbọ́n o kì yóò yà á, òun ni yóò jẹ́ orí, ìwọ yóò jẹ́ ìrù Gbogbo ègun yìí yóò wá sórí rẹ, wọn yóò lé ọ wọn yóò sì bá ọ títí tí ìwọ yóò fi parun, nítorí ìwọ kò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò sì kíyèsí àṣẹ àti òfin tí ó fi fún ọ Wọn yóò jẹ́ àmì àti ìyanu fún ọ àti fún irú ọmọ rẹ títí láé Nítorí ìwọ kò sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ní ayọ̀ àti inú dídùn ní àkókò àlàáfíà Nítorí náà nínú ebi àti òùngbẹ, nínú ìhòòhò àti àìní búburú, ìwọ yóò sin àwọn ọ̀ta à rẹ tí Olúwa rán sí ọ Yóò sì fi àjàgà irin bọ̀ ọ́ ní ọrùn, títí yóò fi run ọ́ Olúwa yóò mú àwọn orílẹ̀ èdè wá sí ọ láti ọ̀nà jínjìn, bí òpin ayé, bí idì ti ń bẹ́ láti orí òkè sílẹ̀, orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò gbọ́ èdè wọn Orílẹ̀ èdè tí ó rorò tí kò ní ojúrere fún àgbà tàbí àánú fún ọmọdé Wọn yóò jẹ ohun ọ̀sìn rẹ run àti àwọn èṣo ilẹ̀ rẹ títí tí ìwọ yóò fi parun Wọn kì yóò fi hóró irúgbìn kan fún ọ, wáìnì túntún tàbí òróró, tàbí agbo ẹran màlúù rẹ kankan tàbí ọ̀wọ́ ẹran àgùntàn rẹ títí ìwọ yóò fi run Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú ù rẹ títí tí odi ìdáàbòbò gíga yẹn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé yóò fi wó lulẹ̀ Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú ù rẹ jákèjádò ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ Nítorí ìyà tí ọ̀ta à rẹ yóò fi jẹ ọ́ nígbà ìgbógun tì, ìwọ yóò jẹ, ẹran ara ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí Olúwa Ọlọ́run ti fi fún ọ Ènìyàn jẹ́jẹ́ àti onímọ̀ jùlọ kò ní ní àánú fún arákùnrin ara rẹ̀ tàbí ìyàwó tí ó fẹ́ràn tàbí àwọn ọmọ rẹ̀ tí o wà láàyè, Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fún ẹnikẹ́ni nínú ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó ń jẹ, nítorí kò sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún un nínú ìdótì náà àti ìpọ́njú tí àwọn ọ̀ta yóò fi pọ́n ọ lójú ní ìlú u rẹ Obìnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú u yín, tí ó si ṣe ẹlẹgẹ́, tí kò jẹ́ dáṣà láti fi àtẹ́lẹṣẹ̀ ẹ rẹ̀ kan ilẹ̀ nítorí ìkẹ́ra àti ìwà ẹlẹgẹ́, ojú u rẹ̀ yóò korò sí ọkọ oókan àyà a rẹ̀, àti sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ rẹ̀ obìnrin ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí láti inú u rẹ̀ àti àwọn ọmọ tí ó ti bí Nítorí ó fẹ́ láti jẹ wọ́n ní ìkọ̀kọ̀ nígbà ìgbógun tì àti ní ìgbà ìpọ́njú tí ọ̀ta rẹ yóò fi jẹ ọ́ nínú àwọn ìlú rẹ Bí ìwọ kò bá rọra tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí, tí a kọ sínú ìwé yìí, tí ìwọ kò sì bọlá fún ògo yìí àti orúkọ dáradára orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ, Olúwa yóò rán ìyọnu tí ó ní ìbẹ̀rù sórí rẹ, àti sórí irú ọmọ ọ̀ rẹ, àti àwọn àjálù pípẹ́, àti ìmúna àti àìsàn ìlọ́ra Olúwa yóò mú gbogbo àrùn Éjíbítì tí ó mú ẹ̀rù bà ọ́ wá sórí ì rẹ, wọn yóò sì so mọ́ ọ Olúwa yóò tún mú onírúurú àìsàn àti ìpọ́njú tí a kò kọ sínú ÌWÉ ÒFIN yìí wá sórí ì rẹ, títí ìwọ yóò fi run Ìwọ tí ó dàbí àìmòye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò sẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ Gẹ́gẹ́ bí ó ti dùn mọ́ Olúwa nínú láti mú ọ ṣe rere àti láti pọ̀ si ní iye, bẹ́ẹ̀ ni yóò dùn mọ́ ọ nínú láti bì ọ́ ṣubú kí ó sì pa ọ́ run Ìwọ yóò di fífà tu kúrò lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní Nígbà náà ni Olúwa yóò fọ́n ọ ká láàrin gbogbo orílẹ̀ èdè, láti òpin kan ní ayé sí òmíràn Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti sin ọlọ́run mìíràn ọlọ́run igi àti ti òkúta Èyí tí ìwọ àti àwọn baba rẹ kò mọ̀ Ìwọ kì yóò sinmi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè náà, kò sí ibi ìsinmi fún àtẹ́lẹ́ṣẹ̀ rẹ Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti fún ọ ní ọkàn ìnàngà, àárẹ̀ ojú, àti àìnírètí àyà Ìwọ yóò gbé ní ìdádúró ṣinṣin, kún fún ìbẹ̀rù-bojo lọ́sàn án àti lóru, bẹ́ẹ̀ kọ́ láé ni ìwọ yóò rí i ní àrídájú wíwà láyé rẹ Ìwọ yóò wí ní òwúrọ̀ pé, Bí ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ níkan ni! nítorí ẹ̀rù tí yóò gba ọkàn rẹ àti ìran tí ojú rẹ yóò máa rí Olúwa yóò rán ọ padà nínú ọkọ̀ sí Éjíbítì sí ìrìnàjò tí mo ní ìwọ kì yóò lọ mọ́ Níbẹ̀ ni ìwọ yóò tún fi ara rẹ fún àwọn ọ̀ta à rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò rà ọ́ Ìsọdi Túntún Májẹ̀mú Èyí ni àwọn ìpinnu májẹ̀mú tí Olúwa pa láṣẹ fún Mósè láti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Móábù, ní àfikún májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú u wọn ní Hórébù, Móṣè pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì sọ fún wọn wí pé Ojú rẹ ti rí gbogbo ohun tí Olúwa ti ṣe ní Éjíbítì sí Fáráò àti, sí gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀ àti sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀ Pẹ̀lú ojú ara rẹ ni ìwọ rí àwọn ìdánwò ńlá náà, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí Olúwa kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ Nígbà ogójì ọdún tí mò ń tọ́ yín sọ́nà ní ihà, aṣọ ọ̀ rẹ kò gbó tàbí bàtà ẹṣẹ̀ rẹ O kò jẹ oúnjẹ tàbí mu wáìnì kankan tàbí rú ohun mímu mìíràn Mo ṣe èyí kí o lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ Nígbà tí o dé ibí yìí, Ṣíhónì ọba Hésíbónì àti Ógù ọba Básánì jáde wá láti bá ọ jà, ṣùgbọ́n a sẹ́gun wọn A gba ilẹ̀ wọn a sì fi fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àti àwọn ọmọ Gádì, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè bí ogún Rọra máa tẹ̀lé ìpinnu májẹ̀mú yìí, kí o lè ṣe rere nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe Gbogbo yín ń dúró lónìí yìí níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ adarí ì rẹ àti olórí àwọn ọkùnrin, àwọn àgbààgbà rẹ àti àwọn olóyè àti gbogbo àwọn ọkùnrin mìíràn ní Ísírẹ́lì, pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọ̀ rẹ àti ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlejò tí wọ́n ń gbé ní àgọ́ ọ̀ rẹ, tí ó ké pópòpó igi rẹ, tí ó sì gbé omi ì rẹ O dúró níhìn ín yìí kí o lè wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, májẹ̀mú tí Olúwa ń ṣe pẹ̀lú ù rẹ lónìí yìí àti tí óun dè pẹ̀lú ìbúra, láti jẹ́wọ́ rẹ lónìí yìí bí ènìyàn an rẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ Ọlọ́run rẹ bí ó ti ṣèlérí àti bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba à rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù Èmi ń ṣe májẹ̀mú yìí, pẹ̀lú ìbúra rẹ̀, kì í ṣe fún ìwọ nìkan tí ó dúró níbí pẹ̀lú wa lónìí níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ṣùgbọ́n àti fún gbogbo àwọn tí kò sí níbí lónìí Ìwọ fúnra à rẹ mọ bí a ṣe gbé ní Éjíbítì àti bí a se kọjá láàrin àwọn orílẹ̀ èdè nílẹ̀ ibí yìí Ìwọ rí láàrin wọn ìríra wọn, àwọn ère àti àwọn òrìṣà igi àti ti òkúta, ti fàdákà àti ti wúrà Rí i dájú pé kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin, ìdílé tàbí ẹ̀yà láàrin yín lónìí tí ọkàn an rẹ̀ yóò yí kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa láti lọ àtí láti sin àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀ èdè náà rí i dájú pé kò sí gbòǹgbò tí ó ń mú irú èso kíkan bẹ́ẹ̀ jáde láàrin yín Nígbà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá gbọ́ ìbúra yìí, kí ó gbàdúrà ìbùkún sórí ara rẹ̀ nígbà náà ni kí ó ronú, Èmi yóò wà lálàáfíà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fi àáké kọ́rí nípa lílọ nínú ọ̀nà ti ara à mi Èyí yóò mú ìjálù wá sórí ilẹ̀ tútù àti sórí ilẹ̀ gbígbẹ bákan náà Olúwa kì yóò ní ìfẹ́ sí àti dáríjìí ìbínú àti ìtara rẹ̀ yóò jó ọkùnrin náà Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sínú ìwé yìí yóò wá sórí i rẹ̀, Olúwa yóò sì yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lábẹ́ ọ̀run Olúwa yóò sì yọ òun nìkan kúrò nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì fún àjálù, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ègún májẹ̀mú tí a kọ sí inú ìwé òfin yìí Àwọn ọmọ rẹ tí ó tẹ̀lé ìran rẹ lẹ́yìn àti àwọn àlejò tí ó wá láti ilẹ̀ jíjìn yóò rí wàhálà tí ó wá sórí ilẹ̀ àti àwọn àrùn pẹ̀lú tí Olúwa mú bá ọ Gbogbo ilẹ̀ náà yóò di imí-òórùn, àti iyọ̀, àti ìjóná tí a kò lè fi ọkàn sí, tàbí tí kò lè ṣo èso tàbí tí koríko kò lè hù nínú u rẹ̀, yóò dàbí ìbìṣubú Ṣódómù àti Gòmórà, Ádímà àti Sébóíímù, tí Olúwa bì subú nínú ìbínú u rẹ̀, àti ìkannú rẹ̀ Gbogbo orílẹ̀ èdè yóò béèrè pé, Kí ló dé tí Olúwa fi ṣe èyí sí ilẹ̀ yìí Kí ni a lè mọ ooru ìbínú ńlá yìí sí Ìdáhùn yóò sì jẹ́ báyìí Nítorí tí ènìyàn yìí kọ̀ Olúwa Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀, májẹ̀mú tí ó ti bá wọn dá nígbà tí ó mú wọn jáde wá láti Éjíbítì Wọ́n lọ wọ́n sì sin ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì forí balẹ̀ fún wọn, ọlọ́run tí wọn kò mọ̀, ọlọ́run tí kò fi fún wọn Nígbà náà ni ìbínú Olúwa ru sí ilẹ̀ wọn, débi pé ó mú gbogbo ègún tí a kọ sínú ìwé yìí wá sórí i rẹ̀ Ní ìbínú àti ní ìkannú, àti ní ìrunú ńlá, Olúwa sì fà wọ́n tu kúrò ní ilẹ̀ wọn, ó sì lé wọn lọ sí ilẹ̀ mìíràn, bí ó ti rí ní òní yìí Ohun ìkọ̀kọ̀ jẹ́ ti Olúwa Ọlọ́run wa, ṣùgbọ́n ohun tí a fi hàn jẹ́ ti wa àti ti àwọn ọmọ wa títí láé, kí a lè tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí Ìṣẹ́gun Ógù Ọba Básánì Lẹ́yìn èyí ní a yípadà tí a sì kọrí sí ọ̀nà tí ó lọ sí Báṣánì, Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ ṣígun wá pàdé wa ní Édíréì Olúwa sọ fún mi pé, Má ṣe bẹ̀rù u rẹ̀ torí pé mo ti fi lé e yín lọ́wọ́ pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ Bí ẹ tí ṣe sí Ṣíhónì ọba Ámórì, tí ó jọba ní Héṣíbónì ni kí ẹ ṣe sí i Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run wa fi Ógù ọba Báṣánì àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lé wa lọ́wọ́ A pa wọ́n run láìṣẹ́ku ẹnì kankan Ní ìgbà náà ní a gba gbogbo àwọn ìlú rẹ̀ Kò sí ọ̀kankan tí a kò gbà nínú àwọn ọgọta ìlú tí wọ́n ní Gbogbo agbégbé Ágóbù, lábẹ́ ìjọba Ógù ní Báṣánì Gbogbo ìlú wọ̀nyí ní a mọ odi gíga yíká pẹ̀lú àwọn ìlẹ̀kùn àti irin Ọ̀pọ̀ àwọn ìlú kékèké tí a kò mọ odi yíká sì tún wà pẹ̀lú Gbogbo wọn ni a parun pátapáta gẹ́gẹ́ bí á ti ṣe sí Síhónì ọba Hésíbónì, tí a pa gbogbo ìlú wọn run pátapáta tọkùnrin tobìnrin àti àwọn ọmọ wọn Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀ṣìn àti ìkógún àwọn ìlú wọn, fún ara wa Ní ìgbà náà ni a ti gba ilẹ̀ tí ó wà ní Jọ́dánì láti odò Ánónì, títí dé orí òkè Hámónì lọ́wọ́ àwọn ọba Ámórì méjèèjì wọ̀nyí Gbogbo àwọn ìlú tí o wà ní orí òkè olórí títẹ́ náà ni a gbà àti gbogbo Gílíádì, àti gbogbo Báṣánì, títí dé Ṣálékà, àti Édíréì, ìlú àwọn ọba Ógù ní ilẹ̀ Báṣánì Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Áréórì níbi odò Ánónì, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gílíádì pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn Gbogbo ìyókù Gílíádì àti gbogbo Básánì, ní ilẹ̀ ọba Ógù ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè Mo sì fi Gílíádì fún Mákírì, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti Gádì ni mo fún ní ilẹ̀ láti Gílíádì lọ dé odò Ánónì títí ó fi dé odò Jábókù Èyí tí i ṣe ààlà àwọn ará Ámónì Apá ìwọ̀ óòrùn rẹ̀ ni Jọ́dánì, ní aginjù, láti Kínérétì títí dé òkun aginjù ní ihà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà Mo pàṣẹ fún un yín ní ìgbà náà pé, Olúwa Ọlọ́run yín ti fi ilẹ̀ yìí fún un yín láti ni ín Ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn ọkùnrin yín tí ó lera tí wọ́n sì ti dira ogun, gbọdọ̀ kọjá ṣíwájú àwọn arákùnrin yín ará Ísírẹ́lì Àwọn ẹ̀yà a yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ohun ọ̀sìn in yín lè dúró ní àwọn ìlú tí mo fi fún un yín, títí di ìgbà tí Olúwa yóò fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún un yín, àti ìgbà tí àwọn náà yóò fi gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún wọn ní ìhà kejì Jọ́dánì Nígbà náà ni ọ̀kọ̀ọ̀kan yín tó lè padà lọ sí ìní rẹ̀ tí mo fún un Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún Jósúà pé, Ìwọ tí fi ojú rẹ rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ṣe sí àwọn ọba méjèèjì wọ̀nyí Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò ṣe sí àwọn ilẹ̀ ọba tí ẹ̀yin n lọ Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, Olúwa Ọlọ́run yín tìkálára rẹ̀ ni yóò jà fún un yín Nígbà náà ni mo bẹ Olúwa wí pé, Ọlọ́run Alágbára, ìwọ tí ń fi títóbi rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ han ìránṣẹ́ rẹ Ọlọ́run wo ló tó bẹ́ẹ̀ láyé àti lọ́run tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára ńlá tí o ti ṣe Jẹ́ kí n kọjá lọ wo ilẹ̀ rere ti ìkọjá Jọ́dánì Ilẹ̀ òkè dídára nì àti Lẹ́bánónì Ṣùgbọ́n torí i ti yín, Olúwa Ọlọ́run bínú sí mi kò sì gbọ́ tèmi Olúwa sọ wí pé, Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ kò gbọdọ̀ sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ yìí sí mi mọ́ Gòkè lọ sí orí òkè Písígà, sì wò yíká ìwọ̀ oòrùn, ìlà oòrun, àríwá àti gúúsù Fi ojú ara rẹ wo ilẹ̀ náà níwọ̀n bí ìwọ kò tí ní kọjá Jọ́dánì yìí Ṣùgbọ́n yan Jósúà, kí o sì gbà á níyànjú, mú un lọ́kàn le, torí pé òun ni yóò ṣíwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọjá, yóò sì jẹ́ kí wọn jogún ilẹ̀ náà tí ìwọ yóò rí Báyi ni a dúró ní àfonífojì ní ẹ̀bá Bétí-Péórì Àlàáfíà lẹ́yìn ìyípadà Ní Ọlọ́run Nígbà tí gbogbo ìbùkún àti ègún wọ̀nyí tí mo ti gbé kalẹ̀ ṣíwájú u yín bá wá sórí i yín àti tí o bá mú wọn sí àyà rẹ níbikíbi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá tú ọ ká sí láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, àti nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ bá yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì gbọ́rọ̀ sí pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un yín lónìí Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ohun ìní rẹ bọ̀ sípò yóò sì ṣàánú fún ọ yóò sì tún ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀ èdè níbi tí ó ti fọ́n ọn yín ká sí Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ẹni rẹ kan sí ilẹ̀ tí ó jìnnà jù lábẹ́ ọ̀run, láti ibẹ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò ṣà yín jọ yóò sì tún mú u yín padà Yóò mú ọ wá sí ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn baba yín, ìwọ yóò sì mú ìní níbẹ̀ Olúwa yóò mú ọ wà ní àlàáfíà kíkún, yóò mú ọ pọ̀ síi ju àwọn baba yín lọ Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò kọ ọkàn rẹ ní ilà àti ọkàn àwọn ọmọ yín, nítorí kí o lè fẹ ẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, àti ayé rẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú gbogbo ẹkún un yín wá sórí àwọn ọ̀ta à rẹ tí wọ́n kórìíra àti tí wọ́n ṣe inúnibíni ì rẹ Ìwọ yóò tún gbọ́ràn sí Olúwa àti tẹ̀lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ ṣe rere nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ, àti nínú gbogbo ọmọ inú ù rẹ, agbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti èṣo ilẹ̀ rẹ Olúwa yóò tún mú inú dídùn sínú ù rẹ yóò sì mú ọ ṣe déédé, gẹ́gẹ́ bí ó ti fi inú dídùn sínú àwọn baba rẹ Bí o bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́ àti àṣẹ tí a kọ sínú ìwé òfin yìí kí o sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ Wàyí gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un yín lónìí kò le jù fún un yín tàbí kọjá agbára yín Kò sí ní ọ̀run, tí ìwọ kò bá fi wí pé, Ta ni yóò gòkè lọ sí ọ̀run fún wa, tí yóò sì mú wa fún wa, kí àwa lè gbọ́, kí a sì le ṣe é Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ìhà kejì òkun, tí ìwọ ìbá fi wí pé, Ta ni yóò rékọjá òkun lọ fún wa, tí yóò sì mú un wá fún wa, kí àwa lè gbọ́ ọ, kí a si le ṣe é Kìí ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà súnmọ́ tòsí ì rẹ, ó wà ní ẹnu ù rẹ àti ní ọkàn rẹ kí ìwọ lè máa ṣe é Wòó mo gbé kalẹ̀ síwájú u yín lónìí, ìyè àti àlàáfíà, ikú àti ìparun Nítorí mo pàṣẹ fún ọ lónìí láti fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, láti rìn ní ọ̀nà a rẹ̀ àti láti pa àwọn àṣẹ, ìpinnu àti òfin rẹ̀ mọ́ Nígbà náà ni ìwọ yóò máa gbé tí o ó sì máa pọ̀ sí i, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún ọ ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní Ṣùgbọ́n tí ọkàn an yín bá yí padà tí ìwọ kò sì ṣe ìgbọ́ràn, àti bí o bá fà, lọ láti foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn àti sìn wọ́n, èmi ń sọ fún un yín lónìí yìí pé ìwọ yóò parun láìsí àní-àní O kò ní í gbé pẹ́ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń kọjá Jọ́dánì láti gbà àti láti ní Lónìí mo pe ọ̀run àti ayé bí ẹlẹ́rìí sí ọ pé mo ti gbékalẹ̀ síwájú rẹ ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún Nísinsìnyìí yan ìyè, nítorí kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lè gbé kí ìwọ sì lè fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, fetí sílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀ Nítorí Olúwa ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù Jósúà Rọ́pò Mósè Nígbà náà ni Móṣè jáde tí ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí gbogbo Ísírẹ́lì pé Mo jẹ́ ọmọ ọgọ́fà ọdún báyìí àti pé èmi kò ni lè darí i yín mọ́ Olúwa ti sọ fún mi pé, O kò ní kọjá Jọ́dánì Olúwa Ọlọ́run rẹ fúnra rẹ̀ ni yóò rékọjá fún ọ Yóò pa àwọn orílẹ̀ èdè yìí run níwájú ù rẹ, ìwọ yóò sì mú ìní ilẹ̀ wọn, Jósúà náà yóò rékọjá fún ọ, bí Olúwa ti sọ Olúwa yóò sì ṣe fún wọn ohun tí ó ti ṣe sí Ṣíhónì àti sí Ógù ọba Ámórì, tí ó parun pẹ̀lú ilẹ̀ ẹ wọn Olúwa yóò fi wọ́n fún ọ, kí o sì ṣe sí wọn gbogbo èyí tí mo ti pa láṣẹ fún ọ Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà Má se bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú ù rẹ Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Nígbà náà ni Mósè pe Jóṣúà ó sì wí fún un níwájú gbogbo Ísírẹ́lì pé, Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí o ní láti lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fún wọn, kí o sì pín ilẹ̀ náà láàrin wọn bí ogún wọn Olúwa fúnra rẹ̀ ń lọ níwájú rẹ yóò sì wà pẹ̀lú ù rẹ kò ní fi ọ́ sìlẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sìlẹ̀ Má ṣe bẹ̀rù má sì ṣe fòyà Nígbà náà ni Móṣè kọ òfin yìí kalẹ̀ ó sì fi fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, tí ń gbé àpótí i májẹ̀mú Olúwa , àti fún gbogbo àwọn àgbà ní Ísírẹ́lì Nígbà náà ni Móṣè pàṣẹ fún wọn, Ní òpin ọdún méje méje, ní àkókò ọdún ìdásílẹ̀, nígbà àjọ àwọn àgọ́ Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì bá wá láti fi ara hàn níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ibi tí yóò yàn, ìwọ yóò ka òfin yìí níwájú wọn sí etí ìgbọ́ wọn Pe àwọn ènìyàn jọ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn àlejò tí ń gbé àwọn ìlú u yín kí wọn lè fetí sí i kí wọn sì lè kọ́ láti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ kí wọn sì rọra tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí Àwọn ọmọ wọn tí wọn kò mọ òfin yìí, gbọdọ̀ gbọ́ kí wọn sì kọ́ láti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ níwọ̀n ìgbà tí o tí ń gbé ní ilẹ̀ tí ò ń kọjá la Jọ́dánì lọ láti ni Olúwa sọ fún Móṣè pé, Ọjọ́ ikú rẹ ti súnmọ́tílé báyìí Pe Jóṣúà kí ẹ sì fi ara yín hàn nínú àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti fi àṣẹ fún un Nígbà náà ni Móṣè àti Jóṣúà wá, wọ́n sì fara wọn hàn níbi àgọ́ àjọ Nígbà náà ni Olúwa farahàn níbi àgọ́ ní ọ̀wọ́ àwọsánmọ̀, àwọ-sánmọ̀ náà sì dúró sókè ẹnu ọ̀nà àgọ́ Olúwa sì sọ fún Móṣè pé Ìwọ ń lọ sinmi pẹ̀lú àwọn baba à rẹ, àwọn wọ̀nyí yóò sì ṣàgbèrè ara wọn sí ọlọ́run àjèjì ilẹ̀ tí wọn ń wọ̀ lọ láìpẹ́ Wọn yóò kọ̀ mí sílẹ̀ wọn yóò sì da májẹ̀mú tí mo bá wọn dá Ní ọjọ́ náà ni èmi yóò bínú sí wọn èmi yóò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò fún wọn, wọn yóò sì parun Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù àti ìṣòro yóò wá sórí wọn, àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò béèrè pé, Ǹjẹ́ ìpọ́njú wọ̀nyí kò wá sórí i wa nítorí Ọlọ́run wa kò sí pẹ̀lú u wa Èmi yóò sì pa ojú mi mọ́ dájúdájú ní ọjọ́ náà nítorí i gbogbo ìwà búburú wọn ní yíyípadà sí ọlọ́run mìíràn Ní báyìí kọ ọ́ kalẹ̀ fúnra à rẹ orin yìí kí o sì kọ ọ́ sí Ísírẹ́lì kí o sì jẹ́ kí wọn kọ ọ́ kí ó lè jẹ́ ẹ̀rí ì mi sí wọn Nígbà tí mo ti mú wọn wá sí ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí ní ìbúra fún àwọn baba ńlá wọn, àti nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí ó sì tẹ́ wọn lọ́rùn, tí wọ́n sì gbilẹ̀, wọn yóò yí padà sí ọlọ́run mìíràn wọn yóò sì sìn wọ́n, wọn yóò kọ̀ mí sílẹ̀, wọn yóò sì da májẹ̀mú mi Àti nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú àti ìṣòro bá wá sórí i wọn, orin yìí yóò jẹ́ ẹ̀rí sí wọn, nítorí kò ní di ìgbàgbé fún àwọn ọmọ wọn Mo mọ̀ ohun tí wọ́n ní inú dídùn sí láti ṣe, pàápàá kí èmi tó mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo ṣe ìlérí fún wọn lórí ìbúra Nígbà náà ni Móṣè kọ orin yìí kalẹ̀ ní ọjọ́ náà ó sì kọ ọ́ sí Ísírẹ́lì Olúwa sì fún Jósúà ọmọ Núnì ní àṣẹ yìí Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí ìwọ yóò mú Ísírẹ́lì wá sí ilẹ̀ tí mo ṣèlérí fún wọn lórí ìbúra, èmi fúnra à mi yóò sì wà pẹ̀lú ù rẹ Lẹ́yìn ìgbà tí Móṣè ti parí i kíkọ ọ̀rọ̀ òfin yìí sínú ìwé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ó sì fi àṣẹ yìí fún àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń gbé àpótí i májẹ̀mú Olúwa Gba ìwé òfin yìí kí o sì fi sí ẹ̀gbẹ́ àpótí i májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run rẹ Níbẹ̀ ni yóò wà bí ẹ̀rí sí ọ Nítorí mo mọ irú ọlọ̀tẹ̀ àti ọlọ́rùn líle tí ẹ jẹ́ Bí o bá ṣe ọlọ̀tẹ̀ sí Olúwa nígbà tí mo pàpà wà láyé Pẹ̀lú u yín, báwo ní ẹ ó ti ṣe ọlọ̀tẹ̀ tó nígbà tí mo bá kú tan! Ẹ péjọ pọ̀ ṣíwájú ù mi gbogbo àgbà ẹ̀yà yín àti àwọn aláṣẹ yín, kí èmi lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí etíìgbọ́ ọ́ wọn Nítorí tí mo mọ̀ pé lẹ́yìn ikú mi, ó dájú pé ìwọ yóò padà di ìbàjẹ́ pátápátá, ẹ ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà tí mo ti pa láṣẹ fún un yín Ní ọjọ́ tó ń bọ̀, ìpọ́njú yóò sọ̀kalẹ̀ sórí i yín nítorí ẹ̀yin yóò ṣe búburú níwájú Olúwa ẹ ó sì mú u bínú nípa ohun tí ọwọ́ ọ yín ti ṣe Móṣè sì ka ọ̀rọ̀ inú orin yìí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin sí etí ìgbọ́ ọ gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì Ikú Móṣè Lórí Òkè Nébò Fetísílẹ̀, Ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀ ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu un mi Jẹ́kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò, kí awọn ọ̀rọ̀ mi máa ṣọ̀kalẹ̀ bí ìrì, bí òjò winiwini sára ewéko túntún, bí ọ̀wàrà òjò sára ohun ọ̀gbìn Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa , Áà, ẹ yìn títóbi Ọlọ́run wa! Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé, gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo Ọlọ́run olótìítọ́ tí kò ṣe àsìṣe kan, Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀ fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apákan tí ó sì doríkodò Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa , Áà ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín, tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín Rántí ìgbà láéláé wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ, àwọn àgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ Nígbà tí atóbijù fi ogún àwọn orílẹ̀ èdè fún wọn, nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn, ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Ísírẹ́lì Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀, Jákọ́bù ni ìpín ìní i rẹ̀ Ní ihà ni ó ti rí i, ní ihà níbi tí ẹranko kò sí Ó yíká, ó sì tọ́jú u rẹ̀, ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀ Bí idì ti íru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ń rábàbà sórí ọmọ rẹ̀, tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sì gbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀ Olúwa samọ̀nà kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀ Ó mú gun ibi gíga ayé ó sì fi èṣo oko bọ́ ọ Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá, àti òróró láti inú akọ òkúta wá, Pẹ̀lú u wàràǹkàsì àti wàrà àgùntàn àti ti àgbò ẹran àti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́ àgùntàn àti ewúrẹ́, pẹ̀lú àgbò irú u ti Báṣánì tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èṣo-àjàrà, àní àti wáìnì Jéṣúrúnì sanra tán ó sì tàpá ìwọ ṣanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọ o sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ Wọ́n sì fi jowú pẹ̀lú ọlọ́run àjèjì i wọn wọ́n sì mú un bínú pẹ̀lú àwọn òrìṣà a wọn Wọ́n rúbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run, ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí, ọlọ́run tí ó sẹ̀sẹ̀ farahàn láìpẹ́, ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù Ìwọ kò rántí Àpáta, tí ó bí ọ o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n, nítorí tí ó ti bínú nítori ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ìn rẹ Ó sì wí pé, Èmi yóò pa ojú ù mi mọ́ kúrò lára wọn, èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí, àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú un wọn Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run, wọ́n sì fi ohun aṣán an wọn mú mi bínú Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀ èdè Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú un mi, yóò sì jó dé ipò ikú ní ìṣàlẹ̀ Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀ yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lórí èmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára Èmi yóò mú wọn gbẹ, ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀ Idà ní òde, àti ìpayà nínú ìyẹ̀wù Ni yóò run ọmọkùnrin àti wúndíá, ọmọ ẹnu-ọmú àti arúgbó eléwù irun pẹ̀lú Mo ní èmi yóò tú wọn ká èmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúró nínú àwọn ènìyàn, nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀ta, kí àwọn ọ̀ta a wọn kí ó má ba à wí pé, Ọwọ́ ọ wa lékè ni kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí   Wọ́n jẹ́ orílẹ̀ èdè tí kò ní ìmọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú un wọn Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọn kí wọn ròbí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí! Báwo ni ẹnì kan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún, tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbàaàrún sá, bí kò ṣe pé Àpáta wọn ti tà wọ́n, bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí Àpáta wa, àní àwọn ọ̀ta wa tìkálára wọn ń ṣe onídàájọ́ Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sódómù àti ti ìgbẹ́ ẹ Gòmórà Èṣo àjàrà wọn kún fún oró, Ìdì wọn korò Ọtí wáìnì ni ìwọ ti dírágónì, àti oró mímú ti pamọ́lẹ̀ Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́ èmi kò sì fi èdìdì dìí ní ìṣúra à mi Ti èmi ni láti gbẹ̀san Èmi yóò san án fún wọn ní àkókò tí ẹ̀sẹ̀ wọn yóò yọ ọjọ́ ìdàmú wọn sún mọ́ etílé ohun tí ó sì ń bọ̀ wá bá wọn yára bọ̀ Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tán tí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ Yóò wí pé Òrìṣà a wọn dà báyìí, àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn, ọlọ́run tí ó jẹ ara ẹbọ wọn tí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n! Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín! Wòó báyìí pé èmi fúnra à mi, èmi ni! Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè, mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná, kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé Èmi ti wà láàyè títí láé, nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán mi àti tí mo bá sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́, Èmi yóò san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá mi Èmi kò sì san fún àwọn tí ó kórìíra à mi Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀, nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran Ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn, orí àwọn asáájú ọlá Ẹyọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀ èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀ta a rẹ̀ yóò sì se ètùtù fún ilẹ̀ rẹ̀ àti ènìyàn Móṣè wà pẹ̀lú u Jóṣúà ọmọ Núnì ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn Nígbà tí Móṣè parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Ísírẹ́lì Ó sọ fún un pé, Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti ṣọ láàrin yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́ran àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí Wọn kì í se ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jọ́dánì lọ láti gbà Ní ọjọ́ kan náà, Olúwa sọ fún Móṣè pé, Gòkè lọ sí Ábárímù sí òkè Nébò ní Móábù, tí ó kọjú sí Jẹ́ríkò, kí o sì wo ilẹ̀ Kénánì ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Isírẹ́lì, bí ìní i wọn Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Árónì ti kú ní orí òkè Hórù tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀ Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ibi omi Móríbà Kádésì ní ihà Ṣínì àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrin àwọn ọmọ Isírẹ́lì Nítorí náà, ìwọ yóò rí ilẹ̀ náà ní ọ̀kánkán, o kì yóò wọ inú rẹ̀ ilẹ̀ ti mo ti fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Móṣè Bùkún Fún Àwọn Ẹ̀yà Èyí ni ìbùkún tí Móṣè ènìyàn Ọlọ́run bùkún fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ó tó kú Ó sì wí pé Olúwa ti Sínáì wá, ó sì yọ sí wọn láti Ṣéírì wá ó sì tàn án jáde láti òkè Páránì wá Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn ún àwọn mímọ́ wá láti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan amúbíiná ti jáde fún wọn wá Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀ Ní ẹṣẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀, òfin tí Móṣè fifún wa, ìní ti ìjọ ènìyàn Jákọ́bù Òun ni ọba lórí Jéṣúrúnì ní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọ pọ̀, pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì Jẹ́ kí Rúbẹ́nì yè kí ó má ṣe kú, tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Júdà Olúwa gbọ́ ohùn Júdà kí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un, kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta rẹ̀! Ní ti Léfì ó wí pé Jẹ́ kí Túmímù àti Úrímù rẹ kí ó wà pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ Ẹni tí ó dánwò ní Másà, ìwọ bá jà ní omi Méríbà Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé, Èmi kò buyì fún wọn Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ Ó kọ́ Jákọ́bù ní ìdájọ́ rẹ̀ àti Ísírẹ́lì ní òfin rẹ̀ Ó mú tùràrí wá ṣíwájú rẹ̀ àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀ Bù sí ohun ìní rẹ̀, Olúwa , kí o sì tẹ́wọ́gba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́ Ní ti Bẹ́ńjámínì ó wí pé Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́, ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrin èjìká rẹ̀ Ní ti Jóṣẹ́fù ó wí pé Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ, fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrì àti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀ àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀ àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Jósẹ́fù, lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀ Ní ọlá ńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀ èdè, pàápàá títí dé òpin ayé Àwọn ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún Éfúráímù, àwọn sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè Ní ti Ṣébúlúnì ó wí pé Yọ̀ Sébúlúnì, ní ti ìjáde lọ rẹ, àti ìwọ Ísákárì, nínú àgọ́ rẹ Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo, wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkun, nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn Ní ti Gádì ó wí pé Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gádì gbilẹ̀! Gádì ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún, ó sì fa apá ya, àní àtàrí Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀ ìpín olórí ni a sì fi fún un Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ, ó mú òdodo Olúwa se, àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ní ti Dánì ó wí pé Ọmọ kìnnìún ni Dánì, tí ń fò láti Básánì wá Ní ti Náfítánì ó wí pé, Ìwọ Náfítánì, Náfítánì kún fún ojú rere Ọlọ́run àti ìbùkún Olúwa yóò jogún ìhà ìwọ̀ oòrùn àti gúṣù Ní ti Áṣérì ó wí pé Ìbùkún ọmọ ni ti Áṣérì jẹ́ kí ó rí ojú rere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kí ó sì ri ẹṣẹ̀ rẹ̀ sínú òróró Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ, agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀ Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jéṣúrúnì, ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ àti ní ojú ọ̀run nínú ọlá ńlá rẹ̀ Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ, àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà Yóò lé àwọn ọ̀ta rẹ níwájú rẹ, ó sì wí pé, Ẹ máa párun! Ísírẹ́lì nìkan yóò jòkòó ní àlàáfíà, oríṣun Jákọ́bù nìkan ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì, níbi tí ọ̀run ti ń ṣẹ ìrì sílẹ̀ Ìbùkún ni fún ọ, Ísírẹ́lì, ta ni ó dà bí ì rẹ, ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa Òun ni àṣà àti ìrànwọ́ rẹ̀ àti idà ọlá ńlá rẹ̀ Àwọn ọ̀ta rẹ yóò tẹríba fún ọ, ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀ Ikú Mósè Nígbà náà ni Móṣè gun òkè Nébò láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù sí orí Písigà tí ó dojú kọ Jẹ́ríkò Níbẹ̀ ni Olúwa ti fi gbogbo ilẹ̀ hàn án láti Gílíádì dé Dánì, gbogbo Náfítanì, ilẹ̀ Éfúrámù àti Mánásè, gbogbo ilẹ̀ Júdà títí dé òkun ìwọ̀-oòrùn Gúṣù àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì Jẹ́ríkò, ìlú ọlọ́pẹ dé Sóárì Nígbà náà ní Olúwa sọ fún un pé, Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù nígbà tí mo wí pé, Èmi yóò fi fún irú ọmọ rẹ Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú ù rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò débẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni Mósè ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ilẹ̀ Móábù, bí Olúwa ti wí Ó sì sin ín nínú àfonífojì ní ilẹ̀ Móábù, tí ó kọjú sí Béhì-Péórì, ṣùgbọ́n títí di òní yìí, kò sí ẹnì kan tí ó mọ ibi tí ibojì i rẹ̀ wà Mósè jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà tí ó kú, síbẹ̀ ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣunkún un Móṣè ní pẹ̀tẹ́lẹ́ Móábù ní ọgbọ̀n ọjọ́ títí di ìgbà tí ọjọ́ ẹkún àti ọ̀fọ̀ Móṣè parí Jóṣúà ọmọ Núnì kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n nítorí Móṣè ti gbọ́wọ́ ọ rẹ̀ lée lórí Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fetí sí i wọ́n sì ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún Mósè Láti ìgbà náà kò sì sí wòlíì tí ó dìde ní Ísírẹ́lì bí i Móṣè, ẹni tí Olúwa mọ̀ lójúkojú, tí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Olúwa rán an láti lọ ṣe ní Éjíbítì sí Fáráò àti sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ àti sí gbogbo ilẹ̀ náà Nítorí kò sí ẹni tí ó tíì fi gbogbo ọ̀rọ̀ agbára hàn, tàbí ṣe gbogbo ẹ̀rù ńlá tí Móṣè fi hàn ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì Mósè Pàṣẹ Ìgbọràn Gbọ́ Ísírẹ́lì, gbọ́ òfin àti ìlànà tí èmi yóò kọ́ ọ yín Ẹ tẹ̀lé wọn kí ẹ ba à lè yè, kí ẹ ba à lè lọ láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín yóò fi fún un yín Ẹ má ṣe fi kún àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún un yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ yọ kúrò nínú wọn, Ṣùgbọ́n ẹ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín tí mo fún un yín mọ́ Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Olúwa ṣe ní Báálí-Péórì Olúwa Ọlọ́run yín run gbogbo àwọn tí ó tẹ̀lé òrìṣà Báálì ti Péórì kúrò ní àárin yín Ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ ni ẹ wà láàyè lónìí Ẹ kíyèsí i, mo ti kọ́ ọ yín ní àwọn òfin àti àṣẹ bí Olúwa Ọlọ́run-ùn mi ti pàṣẹ fún mi, kí ẹ ba à le tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń lọ láti ní ní ìní Ẹ máa kíyèsí wọn dáradára Èyí ni yóò fi ọgbọ́n àti òye yín han àwọn orílẹ̀ èdè Àwọn tí wọn yóò gbọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí wọn yóò sì máa wí pé, Dájúdájú, orílẹ̀ èdè ńlá yìí kún fún ọgbọ́n àti òye Orílẹ̀ èdè olókìkí wo ni Ọlọ́run wọn tún súnmọ́ wọn, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti súnmọ́ wa nígbàkugbà tí a bá ń képè é Orílẹ̀ èdè wo ló tún le lókìkí láti ní àwọn ìlànà òdodo, àti òfin gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin wọ̀nyí tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì sọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láàyè Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní Hórébù, nígbà tí ó wí fún mi pé, Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ ṣíwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn Ẹ̀yin súnmọ́ tòsí ẹ sì dúró ní ẹṣẹ̀ òkè náà, nígbà tí òkè náà yọná lala lọ sókè ọrun pẹ̀lú ìkúùkù ńlá, àti òkùnkùn biribiri Olúwa sì bá yín sọ̀rọ̀ láti àárin iná náà wá Ẹ gbọ́ àwọn ìró ohùn, ṣùgbọ́n ẹ kò rí ẹnikẹ́ni, ohùn nìkan ni ẹ gbọ́ Ó sọ àwọn májẹ̀mú rẹ̀ fún un yín àní àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó pàṣẹ fún un yín láti máa tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sórí sílétì òkúta méjì Olúwa sọ fún mi nígbà tí ẹ gbọdọ̀ tẹ̀lée, nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ ìní yín lẹ́yìn tí ẹ bá la Jọ́dánì kọjá Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí Olúwa bá yín sọ̀rọ̀ ní Hórébù láti àárin iná wá Torí náà ẹ sọ́ra yín gidigidi, kí ẹ ma ba à ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe ère fún ara yín, àní ère lóríṣìíríṣìí yálà èyí tí ó ní ìrísí ọkùnrin tàbí tí obìnrin, tàbí ti ẹranko orí ilẹ̀, tàbí ti ẹyẹ tí ń fò lófuurufú, tàbí ti àwòrán onírúurú ẹ̀dá tí ń fà lórí ilẹ̀, tàbí ti ẹja nínú omi Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ débi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀ èdè lábẹ́ ọ̀run Olúwa Ọlọ́run yín sì ti mú ẹ̀yin jáde kúrò nínú iná ìléru ńlá, àní ní Ị́jíbítì, láti lè jẹ́ ènìyàn ìní i rẹ̀, bí ẹ̀yin ti jẹ́ báyìí Inú Olúwa ru sí mi nítorí yín, ó sì ti búra pé èmi kì yóò la Jọ́dánì kọjá, èmi kì yóò sì wọ ilẹ̀ rere tí Olúwa Ọlọ́run fi fún un yín, ní ìní yín Èmi yóò kú ní ilẹ̀ yìí, èmi kì yóò la Jọ́dánì kọjá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fẹ́ rékọjá sí òdì kejì odò láti gba ilẹ̀ rere náà Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti bá a yín dá Ẹ má ṣe ṣe ère ní ìrísí ohunkóhun fún ara yín, èèwọ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín kà á sí Torí pé iná ajónirun ni Olúwa Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti ní àwọn ọmọ àti àwọn ọmọọmọ, tí ẹ sì ti gbé ní ilẹ̀ yìí pẹ́ Bí ẹ bá wá ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe irú ère yòówù tó jẹ́, tí ẹ sì ṣe búburú lójú Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì mú un bínú Mo pe ọ̀run àti ayé láti jẹ́rìí takò yín lónìí, pé kíákíá ni ẹ ó parun ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń la Jọ́dánì kọjá lọ láti gbà Ẹ kò ní pẹ́ ní ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò run pátapáta Olúwa yóò fọ́n-ọn yín ká sí àárin àwọn ènìyàn náà, àwọn díẹ̀ nínú un yín ni yóò yè láàrin orílẹ̀ èdè tí Olúwa yóò fọ́n ọn yín sí Ẹ ó sì máa sin Ọlọ́run tí àwọn ènìyàn fi ọwọ́ ṣe tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe, èyí tí kò le ríran, gbọ́rọ̀, jẹun tàbí gbọ́ òórùn Bí ẹ̀yin bá wá Olúwa Ọlọ́run yín láti bẹ̀ẹ́ ẹ ó ri i, bí ẹ bá wá a, pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà a yín Bí ẹ bá wà nínú wàhálà, bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀ sí yín, láìpẹ́ ẹ ó tún padà tọ Olúwa Ọlọ́run yín wá, ẹ ó sì gbọ́ tirẹ̀ Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín aláàánú ni, kò ní gbàgbé tàbí pa yín rẹ́ tàbí kó gbàgbé májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín, èyí tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ìbúra Ẹ bèèrè báyìí nípa ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì ṣáájú kí a tó bí i yín, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé Ẹ bèèrè láti igun ọ̀run kan sí èkejì Ǹjẹ́ irú nǹkan olókìkì báyìí ti ṣẹlẹ̀ rí Ǹjẹ́ a ti gbọ́ irú u rẹ̀ rí Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn tí ì gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí, tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti gbọ́ tí ẹ sì yè Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀ èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnra rẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ àmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína ọwọ́, tàbí nípa iṣẹ́ ipá àti agbára ńlá gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Éjíbítì ní ojú ẹ̀yin tìká ara yín A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé Olúwa ni Ọlọ́run Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀ Ó jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, láti kọ́ ọ yín Ní aye, ó fi iná ńlá rẹ̀ hàn yín, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárin iná wá, torí pé ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan àwọn ọmọ wọn ní ipò lẹ́yìn wọn Nípa ìwà láàyè àti nípa agbára ńlá rẹ̀ ni ó fi mú un yín kúrò ní Éjíbítì Láti lé àwọn orílẹ̀ èdè tí ó tóbi tí ó sì lágbára níwájú yín láti le è mú un yín wá sí ilẹ̀ wọn kí ẹ lè jogún rẹ̀ bí ó ti rí lónìí Ẹ gbà kí ẹ sì fi sọ́kàn lónìí pé Olúwa ni Ọlọ́run lókè ọ̀run lọ́hùn ún àti ní ilẹ̀ ní ìṣàlẹ̀ níhìn ín Kò sí òmíràn mọ́ Ẹ pa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ tí mo ń fún un yín lónìí kí ó ba à le è yẹ yín, kí ẹ̀yin sì le è pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín ní gbogbo ìgbà Mósè sì ya àwọn ìlú mẹ́ta kan sọ́tọ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì Níbi tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn le sálọ, bí ó bá ṣe pé ó ṣèèṣì pa aládúgbò rẹ̀ láìsí ìkùnsínú láàrin wọn Òun le sálọ sí èyíkéyìí nínú ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, fún ìgbàlà ẹ̀mí ara rẹ̀ Àwọn ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà nìwọ̀nyí Bésérì ní òkè olórí títẹ́ tí ó wà ní aṣálẹ̀, fún àwọn ará Rúbẹ́nì Rámótì ní Gílíádì fún àwọn ará Gádì àti Gólánì ní Básánì fún àwọn ará Mánásè Èyí ni òfin tí Mósè gbékalẹ̀ fún àwọn ará Ísírẹ́lì Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ ìlànà àti òfin tí Mósè fún wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde kúrò ní Éjíbítì Tí wọ́n sì wà ní ẹ̀bá àfonífojì Bétí Péórì ní ìlà oòrùn Jọ́dánì ní ilẹ̀ Ṣíhónì, ọba àwọn Ámórì tí ó jọba Hésíbónì tí Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, bí wọ́n ṣe ń ti Éjíbítì bọ̀ Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀, àti ilẹ̀ Ógù ọba Básánì àwọn ọba Ámórì méjèèjì tí ń bẹ ní ìlà oòrùn Jọ́dánì Ilẹ̀ wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ láti Áréórì ní etí odò Ánónì dé orí òkè Ṣíhónì Àti gbogbo aginjù ní ìlà oòrùn Jọ́dánì títí dé òkun aginjù ní ìṣàlẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà Àwọn Òfin Mẹ́wàá Mósè sì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ, ó sì wí pé Gbọ́ ìwọ Ísírẹ́lì, gbọ́ ìlànà àti òfin tí mo mú wá sí etíìgbọ ọ yín lónìí Ẹ kọ wọ́n, kí ẹ sì ri dájú pé ẹ̀ ń ṣe wọ́n Olúwa Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú ní Hórébù Kì í ṣe àwọn baba wa ni Olúwa bá dá májẹ̀mú yìí bí kò ṣe àwa, àní pẹ̀lú gbogbo àwa tí a wà láàyè níbí lónìí Olúwa bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú láàrin iná lórí òkè Ó sì wí pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Íjíbitì láti oko ẹrú wá Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú ù mi Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín ní ìrí ohunkóhun lọ́run tàbí ní ilẹ̀ ní ìṣàlẹ̀ níhìn-ín tàbí nínú omi ní ìṣàlẹ̀ Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ láti sìn wọ́n Torí pé èmi Olúwa Ọlọ́run yín Ọlọ́run owú ni mí, tí í fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹ́ta àti ẹ̀kẹ́rin ní ti àwọn tí ó kórìíra mi Ṣùgbọ́n mo ń fí ìfẹ́ han ẹgbẹẹgbẹ̀rùn-ún ìran àwọn tí ó fẹ́ràn mi, tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ Ẹ má ṣe ṣi orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi Ẹ kíyèsí ọjọ́ ìsinmi láti pa á mọ́ bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, kí ẹ ṣe iṣẹ́ ẹ yín pátapáta Ṣùgbọ́n ọjọ́ kéje ni ọjọ́ ìsinmi sí Olúwa Ọlọ́run yín Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà yálà ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí àwọn ọmọ rẹ obìnrin, tàbí àwọn ẹrú ọkùnrin tàbí ẹrú obìnrin yín tàbí màlúù yín, tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín, tàbí èyíkéyìí nínú àwọn ẹran yín, tàbí àwọn àlejò yín, kí àwọn ẹrú-kùnrin àti ẹrú-bìnrin yín le è sinmi, bí i yín Ẹ rántí pé ẹ ti jẹ́ ẹrú ní Éjíbítì rí, àti pé Olúwa Ọlọ́run yín yọ yín kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá, àti nína ọwọ́ rẹ̀ Torí èyí ni Olúwa Ọlọ́run yín ṣe pàṣẹ fún un yín láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́ Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyáà rẹ, bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín, kí ẹ ba à le è pẹ́ láyé, àti kí ó bá à lè dára fún un yín ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín Má ṣe pànìyàn Má ṣe ṣe panṣágà Má ṣe jalè Má ṣe jẹ́rìí èké sí aládùúgbò rẹ Má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí aya aládúgbò rẹ, má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí ilé tàbí ilẹ̀ alábágbé rẹ, sí ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tàbí ohunkóhun tí í ṣe ti aládúgbò rẹ Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ Olúwa tí a kéde rẹ̀ sí gbogbo ìpéjọpọ̀ ọ yín, níbẹ̀ ní orí òkè, láàrin iná, ìkùukù àti òkùnkùn biribiri Kò sì fi ohunkóhun kún un mọ́ Ó sì kọ wọ́n sínú sílétì méjì, Ó sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ Nígbà tí ẹ gbóhùn láti inú òkùnkùn wá, nígbà tí iná náà ń yọná lala, àwọn aṣáájú ẹ̀yà a yín àti àwọn alàgbà a yín tọ̀ mí wá Ẹ sì sọ pé, Olúwa Ọlọ́run wa ti fi ògo rẹ̀ hàn wá, àti títóbi rẹ̀ a sì ti gbóhùn rẹ̀ láti àárin iná wá A ti rí i lónìí pé, ènìyàn sì lè wà láàyè lẹ́yìn tí Olúwa bá bá a sọ̀rọ̀ Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwa yóò fi kú Iná ńlá yìí yóò jó wa run, bí àwa bá sì tún gbọ́ ohun Olúwa Ọlọ́run wa, àwa ó kú Ta ni nínú ẹlẹ́ran ara tí ó ti gbọ́ ohun Olúwa Ọlọ́run láti inú iná rí, bí àwa ti gbọ́ ọ, tí a sì wà láyé Súnmọ́ tòsí ibẹ̀ kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò sọ, nígbà náà sọ ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wa sọ fún ọ fún wa A ó sì fetísílẹ̀, a ó sì gbọ́ran Ọlọ́run ń gbọ́ nígbà tí ẹ̀yin ń bá mi sọ̀rọ̀ Olúwa sì sọ fún mi pé, Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn ènìyàn yí sọ fún ọ Gbogbo ohun tí wọ́n sọ dára, ìbá ti dára tó, bí ọkàn wọn bá lè bẹ̀rù mi, tí ó sì ń pa gbogbo òfin mi mọ́ nígbà gbogbo, kí ó bá à lè dára fún wọn, àti àwọn ọmọ wọn láéláé Lọ sọ fún wọn kí wọn padà sínú àgọ́ wọn Ṣùgbọ́n ìwọ túbọ̀ dúró síbí pẹ̀lú mi, kí n bá à lè fún ọ ní àwọn àsẹ tí o gbọdọ̀ fi kọ́ wọn láti máa tẹ̀lé ní ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún wọn láti ní Torí èyí ẹ sọ́ra láti máa ṣe ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín tí pa ní àṣẹ fún un yín ẹ má ṣe yà sọ́tùn-ún tàbí sósì Ẹ rìn ní gbogbo ọ̀nà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín, kí ẹ bá à le yè, kí ó sì dára fún un yín, kí ọjọ́ ọ yín bá à lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin yóò gbà Fẹ́ràn Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí Olúwa Ọlọ́run yín pàṣẹ fún mi láti kọ́ ọ yín kí ẹ lè kíyèsí i, ní ilẹ̀ náà tí ẹ ó ni lẹ́yìn tí ẹ bá kọjá a Jọ́dánì Kí ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn, lẹ́yìn wọn bá à lè bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá wà láyé, nípa pípa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ tí mo fún un yín mọ́, kí ẹ bá à lè pẹ́ lórí ilẹ̀ Gbọ́ ìwọ Ísírẹ́lì, kí o sì ṣọ́ra láti gbọ́ran, kí ó bá à lè dára fún ọ, kí o bá à lè gbilẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ ti ṣèlérí fún ọ Gbọ́ ìwọ Ísírẹ́lì, Olúwa Ọlọ́run wa, Olúwa kan ṣoṣo ni Fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ Àwọn àṣẹ tí mo fún un yín lónìí gbọdọ̀ má a wà lóókan àyà yín Ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín gidigidi Bí ẹ bá jókòó nínú ilé, ẹ jíròrò nípa wọn, àti nígbà tí ẹ bá ń rìn ní ojú ọ̀nà, bí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde Ẹ ṣo wọ́n sí ọwọ́ yín fún àmì, ẹ so ó mọ́ iwájú orí yín Ẹ kọ wọ́n sára àwọn férémù ìlẹ̀kùn àwọn ilé yín àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde yín Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú ọ dé ilẹ̀ náà tí ó ti búra fún àwọn baba yín Fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù láti fi fún un yín, Ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńláńlá tí kì í ṣe ẹ̀yin ló kọ́ ọ, àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun mèremère tí kì í ṣe ẹ̀yin ló rà wọ́n, àwọn kàǹga tí ẹ kò gbẹ́, àti àwọn ọgbà àjàrà àti èso ólífì tí kì í ṣe ẹ̀yin ló gbìn wọ́n Nígbà tí ẹ bá jẹ tí ẹ sì yó, ẹ sọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé Olúwa , tí o mú un yín jáde láti Éjíbítì wá, kúrò ní oko ẹrú Bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan Ẹ má ṣe tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn ọlọ́run àwọn tí ó yí i yín ká torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọ́run owú ni, ìbínú rẹ̀ yóò sì run yín kúrò ní ilẹ̀ náà Ẹ má ṣe dán Olúwa Ọlọ́run yín wò bí ẹ ti ṣe ní Máṣà Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń pa àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́ àti àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà tí ó ti fún un yín Ẹ ṣe èyí tí ó dára tí ó sì tọ́ lójú Olúwa , kí ó bá à lè dára fún un yín, kí ẹ̀yin bá à lè lọ láti gba ilẹ̀ dáradára náà tí Ọlọ́run ti fi ìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín Ẹ̀yin yóò sì ti àwọn ọ̀ta yín jáde níwájú u yín bí Olúwa ti ṣèlérí Ní ọjọ́ iwájú, bí ọmọ rẹ bá béèrè pé, Kí ni ìtumọ̀ àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin wọ̀nyí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún ọ Sọ fún un pé Ẹrú Fáráò ní ilẹ̀ Éjíbítì ni wá tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa fi ọwọ́ agbára ńlá yọ wá jáde lóko ẹrú Éjíbítì Lójú wa ni Olúwa tí ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí ó lágbára tí ó sì ba ni lẹ́rù lórí Éjíbítì àti Fáráò, àti gbogbo ènìyàn rẹ̀ Ṣùgbọ́n ó mú wa jáde láti ibẹ̀ wá láti mú wa wọ inú àti láti fún wa ní ilẹ̀ tí ó ti fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wa Olúwa pàṣẹ fún wa láti ṣe ìgbọ́ran sí gbogbo ìlànà wọ̀nyí, làti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, kí ó báà lè má a dára fún wa nígbà gbogbo, kí a sì lè wà láyé, bí a se wà títí di òní Bí a bá sọ́ra láti pa gbogbo òfin wọ̀nyí mọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, bí ó ti pàṣẹ fún wa, èyí ni yóò máa jẹ́ òdodo wa Lílé Àwọn Orílẹ̀-Èdè Jáde Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú u yín dé ilẹ̀ náà, tí ẹ ó wọ̀ lọ láti gbà, tí ó sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè kúrò níwájú u yín Àwọn ará Hítì, Gígásì, Ámórì, Kénánì, Pérésì, Hífì àti àwọn ará Jébúsì Àwọn orílẹ̀ èdè méje tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì pọ̀ jù yín lọ, nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá sì ti fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́, tí ẹ sì ti ṣẹ́gun wọn, kí ẹ pa wọ́n run pátapáta Ẹ má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà, ẹ kò sì gbọdọ̀ sàánú un wọn Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ bá wọn dá àna Àwọn ọmọbìnrin yín kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọkùnrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín, torí pé wọ́n á yí àwọn ọmọ yín padà kúrò lẹ́yìn mi, láti jẹ́ kí wọn máa sin òrìṣà, ìbínú Olúwa yóò sì wá sórí yín, yóò sì run yín kíákíá Èyí ni kí ẹ ṣe sí wọn Ẹ wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ bi òpó òkúta ibi mímọ́ òrìṣà wọn lulẹ̀, òpó òrìṣà Áṣérà wọn ni kí ẹ gé lulẹ̀ kí ẹ sì sun ère òrìṣà wọn ní iná Torí pé ènìyàn mímọ́ ni ẹ jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run yín, Olúwa Ọlọ́run yín ti yàn yín láàrin gbogbo ènìyàn lórílẹ̀ ayé, láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀ ohun ìní iyebíye rẹ̀ Olúwa kò torí pé ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ju àwọn ènìyàn yóòkù lọ yàn yín, ẹ̀yin sáà lẹ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn Ṣùgbọ́n torí Ọlọ́run fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó se fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Fáráò ọba Éjíbítì Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé Olúwa Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olótìítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ Ṣùgbọ́n àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ni yóò san ẹ̀san fún ní gbangba nípa pípa wọ́n run kì yóò sì jáfara láti san ẹ̀san fún àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ní gbangba Nítorí náà ẹ kíyési láti máa tẹ̀lé àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí mo fun un yín lónìí Bí ẹ bá ń kíyèsí àwọn òfin wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣọ́ra láti ṣe wọ́n, nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún un yín, bí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín Yóò fẹ́ràn yín, yóò bùkún un yín yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i Yóò bùkún èṣo inú un yín, ọ̀gbìn ilẹ̀ yín, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun àti òróró yín, àwọn màlúù, agbo ẹran yín, àti àwọn àgùntàn, ọ̀wọ́ ẹran yín, ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá yín láti fún un yín A ó bùkún un yín ju gbogbo ènìyàn lọ, kò sí ẹni tí yóò yàgàn nínú ọkùnrin tàbí obìnrin yín, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀kan nínú àwọn ohun ọ̀sìn in yín tí yóò wà láìlọ́mọ Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú àrùn gbogbo, kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí àrùn búburú tí ẹ mọ̀ ní Éjíbítì wá sára yín, ṣùgbọ́n yóò fi wọ́n lé ara gbogbo àwọn tí ó kórìíra yín Gbogbo àwọn ènìyàn tí Olúwa Ọlọ́run yín fi lé yín lọ́wọ́ ni kí ẹ parun pátapáta Ẹ má ṣe sàánú fún wọn, ẹ má ṣe sin olúwa ọlọ́run wọn torí pé ìdánwò ni èyí jẹ́ fún un yín Ẹ lè máa rò láàrin ara yín pé, Àwọn orílẹ̀ èdè yìí lágbára jù wá lọ Báwo ni a o ṣe lé wọn jáde Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn Ẹ rántí dáradára ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe sí Fáráò àti gbogbo Éjíbítì Ẹ sáà fi ojú u yín rí àwọn àdánwò ńlá, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá, ọwọ́ agbára àti nínà ọwọ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi mú un yín jáde Olúwa Ọlọ́run yín yóò ṣe bákan náà sí gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ẹ ń bẹ̀rù Pẹ̀lúpẹ̀lù, Olúwa Ọlọ́run yín yóò rán oyin sáàrin wọn títí tí àwọn tí ó sálà tí wọ́n sápamọ́ fún un yín, yóò fí ṣègbé Ẹ má gbọ̀n jìnnìjìnnì torí wọn, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọ́run alágbára ni, àti Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín yóò lé gbogbo orílẹ̀ èdè wọ̀n-ọn-nì kúrò níwájú u yín díẹ̀díẹ̀ A kò ní gbà yín láàyè láti lé wọn dànù lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo Kí àwọn ẹranko ìgbẹ́ má baà gbilẹ̀ sí i láàrin yín Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi wọ́n lée yín lọ́wọ́, yóò sì máa fà wọ́n sínú un dàrúdàpọ̀ títí tí wọn yóò fi run Yóò fi àwọn ọba wọn lé e yín lọ́wọ́, ẹ̀yin ó sì pa orúkọ wọn rẹ́ lábẹ́ ọ̀run Kò sí ẹni tí yóò lè dojú ìjà kọ yín títí tí ẹ ó fi pa wọ́n run Dá iná sun àwọn ère òrìṣà wọn, ẹ má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí fàdákà tàbí wúrà tí ó wà lára wọn Ẹ má ṣe mú un fún ara yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò jẹ́ ìdẹkùn fún un yín, torí pé ìríra ni sí Olúwa Ọlọ́run yín Ẹ má ṣe mú ohun ìríra wá sí ilé yín, kí ìwọ má bàá di ẹni ìparun bí i rẹ̀ Ẹ kóríra rẹ̀ kí ẹ sì kàá sí ìríra pátapáta, torí pé a yà á sọ́tọ̀ fún ìparun ni Má Ṣe Gbàgbé Ẹ kíyèsí láti máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí mo fún un yín lónìí, kí ẹ báà le yè kí ẹ sì pọ̀ sí i wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le gba ilẹ̀ náà, tí Olúwa fìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín Ẹ rántí bí Olúwa Ọlọ́run yín ti tọ́ ọ yín sọ́nà ní gbogbo ọ̀nà ní ihà fún ogójì ọdún wọ̀nyí láti tẹ orí i yín ba àti láti dán an yín wò kí ó báà le mọ bí ọkàn yín ti rí, bóyá ẹ ó pa òfin rẹ̀ mọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ Ó rẹ̀ yín sílẹ̀ nípa fífi ebi pa yín, Ó sì fi mánà bọ́ ọ yín, èyí tí ẹ kò mọ̀, tí àwọn baba yín kò mọ̀, kí ó báà lè kọ́ ọ yín pé, ènìyàn kò wà láàyè nípa oúnjẹ nìkan, bí kò ṣe ohun gbogbo tí ó jáde láti ẹnu Olúwa wá Aṣọ yín kò gbó mọ́ ọ yín lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ní ẹṣẹ̀ yín kò sì wú, ní ogójì ọdún náà Ẹ mọ̀ ní ọkàn an yín pé, bí baba ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín ń kọ́ ọ yín Torí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀ Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń ṣàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà bálì, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pómégíránátì, òróró ólífì àti oyin Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá Nígbà tí ẹ bá ti jẹ tí ẹ sì yó tán ẹ yin Olúwa Ọlọ́run yín fún pípèṣè ilẹ̀ rere fún un yín Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́ Kí ó má baà jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀, nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i, nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbé ga, tí ẹ ó sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá, nínú oko ẹrú Òun ni ó mú un yín la ihà ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òùngbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńláńlá àti àkéekèe Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta Ó fún yín ní mánà láti jẹ nínú ihà, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun báà le tẹ orí i yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó báà lè dára fún-un yín Ẹ lè rò nínú ara yín pé, Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi Ṣùgbọ́n ẹ rántí Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fún un yín lókun àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí Bí ẹ bá wá gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn, tí ẹ sì sìn wọ́n, tí ẹ sì foríbalẹ̀ fún wọn, Mo kìlọ̀ fún un yín pé rírun ni ẹ ó run Bí àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa parun níwájú u yín, bákan náà ni ẹ ó parun, torí pé ẹ kò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín lẹ́nu Kì í Se Nítorí Òdodo Ísírẹ́lì Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì Báyìí, ẹ ti gbáradì látí la Jọ́dánì kọjá, láti lọ gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ, tí wọ́n ní àwọn ìlú ńláńlá, tí odi wọn kan ọ̀run Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga àní àwọn ọmọ Ánákì ni wọ́n Ẹ gbọ́ nípa wọn, ẹ sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa wọn pé, Ta ni ó le è dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Ánákì Ṣùgbọ́n kí ó dá a yín lójú lónìí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ń ṣáájú u yín lọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun Yóò jó wọn run, yóò sì tẹ orí wọn ba níwájú yín Ẹ ó sì lé wọ́n jáde, ẹ ó sì run wọ́n kíákíá, bí Olúwa ti ṣèlérí fún un yín Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti lé wọn jáde níwájú u yín, ẹ má ṣe wí fún ara yín pé, Torí òdodo mi ní Olúwa se mú mi wá síbí láti gba ilẹ̀ náà Rárá, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ni Ọlọ́run yóò se lé wọn jáde níwájú u yín Kì í se nítorí òdodo yín, tàbí ìdúróṣinṣin ni ẹ ó fí wọ ìlú wọn lọ láti gba ilẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi lé wọn jáde kúrò níwájú u yín láti lè mú ohun tí ó búra fún àwọn baba ṣẹ fún Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù Ṣùgbọ́n kí ó yé yín pé kì í ṣe nítorí òdodo yín ni Olúwa Ọlọ́run yín fi ń fún un yín ní ilẹ̀ rere náà, láti ní, nítorí pé alágídí ènìyàn ni ẹ jẹ́ Ẹ rántí, ẹ má sì ṣe gbàgbé bí ẹ ti mú Olúwa Ọlọ́run yín bínú ní ihà Láti ọjọ́ ti ẹ tí kúrò ní Éjíbítì ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa títí tí ẹ fi dé ìhín yìí Ní Hórébù ẹ mú kí Olúwa bínú, títí débi pé ó fẹ́ run yín Nígbà tí mo gòkè lọ láti lọ gba sílétì òkúta, sílétì májẹ̀mú ti Olúwa ti bá a yín dá Ogójì ọ̀sán àti òru ni mo fi wà lórí òkè náà, èmi kò fẹnu kan oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni ń kò mumi Olúwa fún mi ní òkúta méjì tí a fi ìka Ọlọ́run kọ Lórí wọn ni a kọ àwọn òfin tí Ọlọ́run sọ fún un yín lórí òkè láàrin iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀ sí Lópin ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí, Olúwa fún mi ní sílétì òkúta méjì, sílétì òkúta májẹ̀mú náà Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sọ fún mi pé, Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìnín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Éjíbítì ti hùwà ìbàjẹ́ Wọ́n ti yípadà kíá, nínú àṣẹ mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn Olúwa sì sọ fún mi pé, Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé alágídí ènìyàn gbáà ni wọ́n Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n run wọ́n, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè tí ó lágbára tí ó sì pọ̀ jù wọ́n lọ Báyìí ni mo yípadà, tí mó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí okè náà wá, orí òkè tí o ń yọná Àwọn sílétì májẹ̀mú méjèèjì sì wà lọ́wọ́ mi Gbà tí mo ṣàkíyèsí, mo rí i pé ẹ ti dẹ́sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín Ẹ ti ṣe ère òrìṣà ní ìrí ọ̀dọ́ màlúù, fún ara yín Ẹ ti yípadà kánkán kúrò nínú ọ̀nà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un yín Bẹ́ẹ̀ ni mó ju síléètì méjèèjì náà mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ lójú u yín Lẹ́yìn náà mo tún wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru Èmi kò jẹ oúnjẹ kankan bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu omi, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ tí dá, tí ẹ sì ń ṣe búburú lójú Olúwa , tí ẹ sì ń mú u bínú Mo bẹ̀rù ìbínú àti ìrunú Olúwa , nítorí pé inú bí i sí i yín débi wí pé ó fẹ́ pa yín run Ṣùgbọ́n Olúwa tún fetí sí mi lẹ́ẹ̀kàn síi Inú sì bí Olúwa sí Árónì láti pa á run, nígbà náà ni mo tún gbàdúrà fún Árónì náà Bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú ohun tí ó mú un yín dẹ́sẹ̀, àní ère òrìṣà màlúù tí ẹ ti ṣe, mo sì fi iná sun ún, bẹ́ẹ̀ ni mo gún un, mo sì lọ̀ ọ́ lúúlúú bí eruku lẹ́búlẹ́bú, mo sì da ẹ̀lọ̀ rẹ̀ sínú odò tí ń sàn níṣàlẹ̀ òkè Ẹ̀yin tún mú Olúwa bínú ní Tábérà, Másà àti ní Kíbírò Hátafà Nígbà tí Olúwa ran an yín jáde ní Kadesi Báníyà, Ó wí pé, Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín Ṣùgbọ́n ẹ sọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀ Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín ni ẹ ti ń sọ̀tẹ̀ sí Olúwa Mo ti wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí nítorí pé Olúwa sọ pé Òun yóò pa yín run Mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé, Olúwa Olódùmarè, má ṣe run àwọn ènìyàn rẹ, àní ogún rẹ tí o ti ràpadà, nípa agbára rẹ tí o sì fi agbára ńlá mú wọn jáde láti Éjíbítì wá Rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù Fojú fo orí kunkun àwọn ènìyàn yìí, pẹ̀lú ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti mú wa jáde wá yóò wí pé, Torí pé Olúwa kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ náà tí ó ti ṣèlérí fún wọn, àti pé ó ti kórìíra wọn, ni ó fi mú wọn jáde láti pa wọ́n ní ihà Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn rẹ ni wọ́n, ogún rẹ tí o ti fi ọwọ́ agbára rẹ àti nínà ọwọ́ rẹ mú jáde Aṣán Ni Ohun Ayé Ọ̀rọ̀ Oníwàásù, ọmọ Dáfídì, ọba Jérúsálẹ́mù Aṣán! Aṣán! ni oníwàásù wí pé Aṣán pátapáta! Gbogbo rẹ̀ aṣán ni Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ, síbẹ̀ ayé dúró títí láé Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀, ó sì sáré padà síbi tí ó tí yọ Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ihá gúṣù, Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá, a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀ Gbogbo odò ń sàn sí inú òkun síbẹ̀síbẹ̀ òkun kò kún níbi tí àwọn odò ti wá, níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí Ohun gbogbo ni ó ń mú àárẹ̀ wá, ju èyí tí ẹnu le è ṣọ ojú kò tí ì rí ìrírí tí ó tẹ́ẹ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni, etí kò tí ì kún fún gbígbọ́ Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóò sì máa wà, ohun tí a ti ṣe sẹ́yìn òun ni a ó tún máa ṣe padà kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è ṣọ wí pé, Wòó! Ohun tuntun ni èyí Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́ Ó ti wà ṣáájú tiwa Kò sí ìrántí ohun ìṣáájú bẹ́ẹ̀ ni ìrantí kì yóò sí fún ohun ìkẹyìn tí ń bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn tí ń bọ̀ ní ìgbà ìkẹyìn Èmi, Oníwàásù ti jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì ní Jérúsálẹ́mù rí Mo fi àsìkò mi sílẹ̀ láti kọ́ àti láti ṣe àwárí pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run Háà ẹrù wúwo tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ènìyàn Èmi ti rí ohun gbogbo tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, gbogbo rẹ̀ kò ní ìtumọ̀ bí ẹní gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni Ohun tí ó ti wọ́ kò le è ṣe é tọ́ mọ́, ohun tí kò sí kò le è ṣe é kà Mo rò nínú ara mi, Wòó, mo ti dàgbà, ọgbọ́n mi sì ti pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tí ó ti ṣe alákòóṣo Jérúsálẹ́mù síwájú mi lọ, mo ti ní ìrírí púpọ̀ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀ Nígbà náà ni mo fi ara jìn láti ní ìmọ̀ nípa ọgbọ́n, àti pàápàá àìgbọ́n àti àgọ̀, ṣùgbọ́n mo rí, wí pé èyí pẹ̀lú bí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni Nítorí pé ọgbọ́n púpọ̀ ìbànújẹ́ púpọ̀ ní ń mú wá, bí ìmọ̀ bá sì ṣe pọ̀ tó náà ni ìbànújẹ́ ń pọ̀ tó Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún ìpara ní òórùn burúkú, bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀ Ọkàn ọlọgbọ́n a máa sí sí ohun tí ó tọ̀nà, ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára Kó dà bí ó ti ṣe ń rìn láàrin ọ̀nà, òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́n a sì máa fi han gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ, ma ṣe fi àyè rẹ sílẹ̀ ìdákẹ́jẹ́jẹ́ le è tu àṣìṣe ńlá Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn, irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jù lọ, nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn àyè tí ó kéré jù lọ Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin, nígbà tí ọmọ aládé ń fi ẹṣẹ̀ rìn bí ẹrú Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán-an Ẹnikẹ́ni tí ó bá pe òkúta lẹ́jọ́ le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì-igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn Bí àáké bá kú tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́n yóò nílò agbára púpọ̀ ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá Bí ejò bá sán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀, kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀ Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́ ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnrarẹ̀ ni yóò parun Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀ ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìṣínwín búburú Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀ kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀ ta ni ó le è ṣọ fún-un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ Iṣẹ́ aṣiwèrè a máa dá lágbara kò sì mọ ojú ọ̀nà sí ìgboro Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìranṣẹ́ rẹ̀ àti tí àwọn ọmọ aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀ Ìbùkún ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ èyí tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọlọ́lá, àti tí àwọn ọmọ aládé ń jẹun ní àsìkò tí ó yẹ, fún ìlera, tí kì í ṣe fún ìmọ̀tí para Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, ilé a máa wú, bí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó Ẹ̀rín rínrín ni a ṣe àṣè fún, wáìnì a máa mú ayé dùn, ṣùgbọ́n owó ni ìdáhùn sí ohun—gbogbo Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ, tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ìbùsùn rẹ, nítorí pé ẹyẹ ojú—ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹ ẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn Àkàrà Lórí Omi Fún àkàrà rẹ ṣórí omi, nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò ríi padà Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú, nítorí ìwọ kò mọ ohun—ìparun tí ó le è wá ṣórí ilẹ̀ Bí àwọ̀ṣánmọ̀ bá kún fún omi, ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí Bí igi wó sí ì hà Gúṣù tàbí sí ìhà àríwá níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọ̀ṣańmọ̀ kò ní kórè Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ tàbí mọ bí ara tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́dàá ohun-gbogbo Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọ̀lẹ ní àṣálẹ́, nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere bóyá èyí tàbí ìyẹn tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákàn náà Ìmọ́lẹ̀ dùn Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún tí ó le è lò láyé ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn nítorí wọn ó pọ̀ Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwe kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹ àti ohunkóhun tí ojú rẹ rí ṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́ Nítorí náà, mú ìjayà kúrò ní ọkàn rẹ kí o sì lé ìbànújẹ́ ara rẹ kúrò nítorí èwe àti kékeré kò ní ìtumọ̀ Òpin Gbogbo Ọ̀rọ̀ Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ ní ọjọ́ èwe rẹ, nígbà tí ọjọ́ ibi kò tíì dé àti tí ọdún kò tíì ní ṣun mọ́ etílé, nígbà tí ìwọ yóò wí pé, Èmi kò ní ìdùnnú nínú wọn Kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀ àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn, àti kí àwọ̀ṣánmọ̀ tó padà lẹ́yìn òjò Nígbà tí olùṣọ́ ilé yóò wárìrì tí àwọn ọkùnrin alágbára yóò tẹríba, nígbà tí àwọn tí ó ń lọ̀ dá kẹ́ nítorí pé wọn kò pọ̀, tí àwọn tí ń wo òde láti ojú fèrèsé yóò ṣókùnkùn Nígbà tí ilẹ̀kùn sí ìgboro yóò tì tí ariwo ọlọ yóò dákẹ́ nígbà tí àwọn ènìyàn yóò dìde sí ariwo àwọn ẹyẹ ṣùgbọ́n gbogbo orin wọn yóò máa lọ ilẹ̀ Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gíga àti ti ìfarapa ní ìgboro nígbà tí igi álímọ́ǹdì yóò tanná àti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọ tí ìfẹ́ kò sì ní ru ṣókè mọ́ nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayé tí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro Rántí rẹ̀—kí okùn fàdákà tó já, tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́ kí ìṣa tó fọ́ níbi ìṣun, tàbí kí àyíká-kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà rí, tí ẹ̀mí yóò sì padà ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni Aṣán! Aṣán! ni Oníwàásù wí Gbogbo rẹ̀ aṣán ni! Kì í ṣe wí pé Oníwàásù jẹ́ ọlọ́gbọ́n nìkan, ṣùgbọ́n ó tún kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ Ó rò ó dáradára ó sì ṣe àwárí, ó sì gbé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ òwe kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ Oníwàásù wádìí láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀nà, ohun tí ó kọ sì dúró ṣinṣin ó sì jẹ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn sì dàbí èso tí a kàn pọ̀ dáradára tí olùṣọ́-àgùntàn kan fi fún ni Àti síwájú láti inú èyí, Ọmọ-ọ̀n mi, gba ìmọ̀ràn Nínú ìwé púpọ̀, òpin kò sí, ìwé kíkà púpọ̀ a máa mú ara ṣàárẹ̀ Níṣinsìn yìí, òpin gbogbo ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ ni pé Bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́, nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn Nítorí Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olúkúlùkù iṣẹ́ àti ohun ìkọ̀kọ̀, kì bá à ṣe rere kì bá à ṣe búburú Ìgbádùn Mo rò nínú ọkàn mi, Wá níṣinṣin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára Ṣùgbọ́n eléyìí náà já sí asán Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni Àti fún ire-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀,—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀ Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀ Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn Mo gbé adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi Mo sì tún ní agbo àgùntàn ju ẹnikẹ́ni ní Jérúsálẹ́mù lọ Mo kó wúrà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbéríko Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin Mo sì ní onírúurú àwọn obìnrin tí ọkan ọkùnrin le e fà sí Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù ṣáájú mi Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀ Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́ N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi, èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi Ṣíbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní gbogbo rẹ̀, aṣán ni Ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn ọgbọ́n àti òmùgọ̀, aṣán ni Nígbà náà ni mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ọgbọ́n, àti ìsínwín àti àìgbọ́n kí ni ọba tí ó jẹ lẹ́yìn tí ọba kan kú le è ṣe ju èyí tí ọba ìṣáájú ti ṣe lọ Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀, nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀ wí pé ìpín kan náà ni ó n dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n Mo ṣọ nínú ọkàn mi wí pé, Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú Nítorí pé ọlọgbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́ gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀ ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọgbọ́n ènìyàn Nítorí náà, mo kórìíra ìwà-láàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi Gbogbo rẹ̀ aṣán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni Mo kóòríra gbogbo ohun tí mo ti ṣíṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọgbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí òmùgọ̀ Ṣíbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìṣimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnra rẹ̀ Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìṣinmi ní alẹ́ Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú Ènìyàn kò le è ṣe ohun kóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀ Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run Nítorí wí pé láìsí Ọlọ́run, ta ni ó le è jẹ tàbí ki o rí ìgbádùn Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ni ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹlẹ́ṣẹ̀, o fún-un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun-ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí o tẹ Ọlọ́run lọ́rùn Eléyìí pẹ̀lú, aṣán ni, ó dàbí ẹni a gbìyànjú àti mú Àkókò Àti Ìgbà Wa Fún Ohun Gbogbo Àsìkò wà fún ohun gbogbo àti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú, ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú lára dá ìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́ Ìgbà láti ṣunkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rín ìgbà láti sọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọ ìgbà láti ṣún mọ́ àti ìgbà láti fà ṣẹ́yìn Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiri ìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù, Ìgbà láti ya àti ìgbà láti rán ìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti ṣọ̀rọ̀ Ìgbà láti níìfẹ́ àti ìgbà láti kóríra ìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà Kí ni òṣìṣẹ́ jẹ ní èrè nínú wàhálà rẹ̀ Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, ṣíbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin Mo mọ̀ wí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju pé kí inú wọn dùn kí wọn sì ṣe rere níwọ̀n ìgbà tí wọ́n sì wà láàyè Wí pé kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́ Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀ Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni Ohun tí ó wà ti wà tẹ́lẹ̀, ohun tí ó ń bọ̀ wá ti wà tẹ́lẹ̀, Ọlọ́run yóò sì mú kí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣẹ́yìn tún ṣẹlẹ̀ Mo sì tún rí ohun mìíràn ní abẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́, òdodo ni ó wà ní bẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ní o wà ní bẹ̀ Mo rò nínú ọkàn mi, Ọlọ́run yóò mú ṣẹ sí ìdájọ́ Olótìítọ́ pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀, Nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́, àti àsìkò fún gbogbo ìṣe Mo tún ro pe Ọlọ́run ń dán wa wò láti fi hàn wá wí pé bí ẹranko ni ènìyàn rí Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín ń dúró dè wọ́n Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò ṣàn ju ẹranko lọ, nítorí pé aṣán ni yíyè jẹ́ fún wọn Ibì kan náà ni gbogbo wọn ń lọ, wọ́n wá láti inú erùpẹ̀, inú erùpẹ̀ náà ni wọn yóò tún padà sí Ta ni ó mọ̀ bóyá ẹ̀mí ènìyàn ń lọ sí òkè tí ẹ̀mí ẹranko sì ń lọ sí ìsàlẹ̀ nínú ilẹ̀ ní Nígbà náà, ni mo wá ríi wí pé, kò sí ohun tí ó sàn fún ènìyàn ju kí ó gbádùn iṣẹ́rẹ̀, nítorí pé ìpín tirẹ̀ ni èyí Tàbí ta ni ó le è mú kí ó rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn-in rẹ̀ kò sí! Ìnilára, Wàhálà, Àti Lọ́rẹ̀ẹ́ Mo sì tún wò ó, mo sì ri gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kò sì ní Olùtùnú kankan, agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára wọn kò sì ní olùtùnú kankan Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú tí wọ́n sì ti lọ, ó ṣàn fún wọn ju àwọn tí wọ́n sì wà láàyè lọ Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju àwọn méjèèjì lọ ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrun Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbáratagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùgbò wọn ni Ṣùgbọ́n, aṣán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kò ó sì ba tara rẹ̀ jẹ́ Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́jẹ́jẹ́ pèlú wàhálà, àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ Lẹ́ẹ̀kan síi mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn Ọkùnrin kan dá wà, kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí wàhálà rẹ̀ kò lópin, ṣíbẹ̀, ọ̀rọ̀ ohun ìní rẹ̀ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó bèèrè pé, Nítorí ta ni mo ṣe ń ṣe wàhálà àti wí pé kí ni ìdí tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi Eléyìí náà aṣán ni iṣẹ́ ìbànújẹ́ ni Ẹni méjì ṣàn ju ẹnìkan, nítorí wọ́n ní ààbò rere fún iṣẹ́ wọn Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀, ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fàá sókè, ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn-án lọ́wọ́! Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá ṣùn pọ̀, wọn yóò móoru Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan, àwọn méjì le è gbìjà ara wọn, ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn-ún yàra fà já Òtòsì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó ṣàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn, Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde ìjọba, bí a tilẹ̀ bí i ní talákà ní ìjọba rẹ̀ Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí Gbogbo àwọn tí ó wà ní wájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni Dídúró Nínú Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Ṣọ́ ìrìn rẹ nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run Kí ìwọ kí ó sì múra láti gbọ́ ju àti se ìrúbọ aṣiwèrè, tí kò mọ̀ wí pé òun ń ṣe búburú Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹ má sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́run Ọlọ́run ń bẹ ní ọ̀run Ìwọ sì wà ní ayé, nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n Gẹ́gẹ́ bí àlá tí ń wá, nígbà tí ìtọ́jú púpọ̀ wà bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀jù Nígbà tí ó bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pé ní mímú ṣẹ kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ Ó sàn láti má jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju wí pé kí a jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí a má mu ṣẹ lọ Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ tì ọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀ Má sì ṣe sọ fún òjíṣẹ́ ilé-ìsìn pé Àṣìṣe ni ẹ̀jẹ́ mi Kí ló dé tí Ọlọ́run fi le è bínú sí ọ kí ó sì ba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ jẹ́ Aṣán ni ọ̀pọ̀ àlá àti ọ̀rọ̀ púpọ̀ Nítorí náà dúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run Bí o bá rí talákà tí wọ́n ń ni lára ní ojú títì, tí a sì ń fi òtítọ́ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ dùú, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu láti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹni tí ó wà ní ipò gíga máa ń mọ́ òṣìṣẹ́ tí ó wà lá bẹ́ rẹ̀ lójú ni, ṣìbẹ́ àwọn kan sì wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn méjèèjì Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító, ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún-un Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ síi náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ síi Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí oní nǹkan bí kò se pé, kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rírí wọn Oorun alágbàṣe a máa dùn, yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó ṣùn rárá Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun oní nǹkan Tàbí ọrọ̀ tí ó ṣọnù nípa àìrí ojúrere, nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún-un Ìhòòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀, bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀ Ohun búburú gbáà ni eléyìí pàápàá Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọ kí wá ni èrè tí ó jẹ nígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́ Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ọ rẹ̀, pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀ nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún-un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí Síwájú sí, nígbà tí Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni ní ọrọ̀ àti ohun ìní, tí ó sì fún-un lágbára láti gbádùn wọn, láti gba ìpín rẹ̀ kí inú rẹ̀ sì dùn sí iṣẹ́ rẹ̀—ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí Ó máa ń ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ́kan nípa ọjọ́ ayé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí pé Ọlọ́run ń pa á mọ́ pẹ̀lú inú dídùn ní ọkàn rẹ̀ Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ohun ìní àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohun kóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́ ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfàní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn Aṣán ni èyí, àrùn búburú gbáà ni Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́rún ọmọ kí ó sì wà láàyè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ṣíbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láàyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun-ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo ṣọ wí pé àbíkú ọmọ ṣàn jù ú lọ Ó wà láìní ìtumọ̀, ó lọ nínú òkùnkùn, nínú òkùnkùn sì ni orúkọ rẹ̀ farapamọ́ sí Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìṣinmi ju ti okùnrin náà lọ Kó dà, bí ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rún ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun-ìní rẹ̀ Kìí ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ ni ṣíbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí Kí ni àǹfàní tí ọlọgbọ́n ènìyàn ní lórí aṣiwèrè Kí ni èrè talákà ènìyàn nípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tó kù Ohun tí ojú rí sàn ju ìfẹnúwákiri lọ Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ, ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mímọ̀ kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadì pẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jùú lọ Ọ̀rọ̀ púpọ̀, kì í ní ìtumọ̀ èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀ Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti aṣán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán kò sí! Ọgbọ́n Orúkọ rere ṣàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju ibi àṣè nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn kí alààyè ní èyí ní ọkàn Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ Ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le Ọkàn ọlọgbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkò ni ẹ̀rín òmùgọ̀, Aṣán sì ni eléyìí pẹ̀lú Ìrẹ́jẹ a máa ṣọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ, ṣùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé Má ṣe sọ wí pé, Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti bèèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún-ìní jẹ́ ohun tí ó dára ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní Ọgbọ́n jẹ́ ààbò gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá níi Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe Ta ni ó le è to ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́ Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn, ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó Ọlọ́run tí ó dá èkínní náà ni ó dá ìkejì nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí ohun kankan nípa ọjọ́ iwájúu rẹ̀ Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí Ènìyàn olóòtìítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀ ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀ Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrè Èéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé Ó dára láti mú ọ̀kan kí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀ Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè Ọgbọ́n máa ń mú kí Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára ju alákòóṣo mẹ́wàá lọ ní ìlú Kò sí olódodo ènìyàn kan láyé tí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá Má ṣe kíyè sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmìíràn Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé, Mo pinnu láti jẹ́ ọlọgbọ́n ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́, ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀ ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀ Mó wá ròó nínú ọkàn mi láti mọ̀, láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́n àti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ àgọ́ ìwà búburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀ Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọ obìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì, tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkúté tí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n, ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀ ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀ Oníwàásù wí pé, Wò ó eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo Nígbà tí mo sì ń wá a kiri ṣùgbọ́n tí n kò rí ì mo rí ọkùnrin tí ó dúró dáradára kan láàrin ẹgbẹ̀rún ṣùgbọ́n n kò rí obìnrin, kankan kí ó dúró láàrin gbogbo wọn Eléyìí nìkan ni mo tíì rí Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára, ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ Pa Òfin Ọba Mọ́ Ta ni ó dàbí ọlọgbọ́n ènìyàn Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dán ó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀ Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró ní ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn Níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è ṣọ fún-un wí pé, Kí ni ìwọ ń ṣe Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan, àyà ọlọgbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é Ohun gbogbo ni ó ní àsìkò àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti ṣe, ṣùgbọ́n, òsì ènìyàn pọ̀ sí orí ara rẹ̀ Níwọ̀n ìgbà tí kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́-ọ̀lá, tani ó le è sọ fún-un ohun tí ó ń bọ̀ Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbàá dúró nítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀ Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀ bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀ Gbogbo ǹnkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń mú lò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn Ìgbà kán wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tó kù fún ìpalára rẹ̀ Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú òsìkà—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀ Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òsìkà ènìyàn ń ṣe ọgọ́rùn-ún ibi ṣíbẹ̀ tí ó sì wà láàyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run Ṣíbẹ̀ nítorí tí òsìkà kò bẹ̀rù Ọlọ́run, kò ní dára fún wọn, ọjọ́ wọn kò sì ní gùn bí òjìji Ohun mìíràn tún wà tí kò ní ìtumọ̀, tí ó ń ṣẹlẹ̀ láyé olódodo tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí òsìkà àti òsìkà tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí olódodo Mo ṣọ wí pé eléyìí gan-an kò ní ìtumọ̀ Nítorí náà mo kan sáárá sí ìgbádùn ayé, nítorí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ní abẹ́ oòrùn ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí inú rẹ̀ sì dùn lọ Nígbà náà ni ìdùnú yóò báa rìn nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé ti Ọlọ́run tí fi fún un lábẹ́ oòrùn Nígbà tí mo lo ọkàn mi láti mọ ọgbọ́n àti láti wo wàhálà ènìyàn ní ayé Nígbà náà ni mo rí gbogbo ohun tí Ọlọ́run tí ṣe, kò sí ẹnìkan tí ó le è mòye ohun tí ó ń lọ lábẹ́ oòrùn Láì bìkítà gbogbo ìyànjú rẹ̀ láti wá rí jáde, ènìyàn kò le è mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kódà bí ọlọgbọ́n ènìyàn rò wí pé òun mọ̀ ọ́n, kò le è ní òye rẹ̀ ní pàtó Àyànmọ́ Kan Náà Fún Gbogbo Wọn Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olòtìítọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bó yá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn ń pín—olótìítọ́ àti òsìkà, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rúbọ àti àwọn tí kò rúbọ Bí ó ti wà pẹ̀lú ọkùnrin rere bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀ bí ó ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúra bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìṣínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láàyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrin alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá ṣàn dáadáa ju òkú ẹkùn lọ! Nítorí pé ẹni tí ó wà láàyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan wọn kò ní èrè kankan mọ́, àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn àti ìlara wọn ti parẹ́ láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú-dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìṣinyìí ni Ọlọ́run síjú àánú wo ohun tí o ṣe Má a wọ aṣọ funfun nígbàkugbà kí o sì máa fi òróró yan oríìrẹ nígbà gbogbo Má a jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrun Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣeé pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú iṣà-òkú níbi tí ò ń lọ Mo ti rí ohun mìíràn lábẹ́ oòrùn Eré-ìje kì í ṣe fún ẹni tí ó yára tàbí ogun fún alágbára bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kò wà fún ọlọ́gbọ́n tàbí ọrọ̀ fún ẹni tí ó ní òye tàbí ojú rere fún ẹni tí ó ní ìmọ̀ ṣùgbọ́n ìgbà àti èsì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé Gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburú tàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùn gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibi tí ó ṣubú lù wọ́n láì rò tẹ́lẹ̀ Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yìí po, ó sì kọ́ ilé-ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì síi Ṣùgbọ́n, tálákà ọkùnrin tí ó jẹ ọlọgbọ́n kan ń gbé ní ìlú náà, ó sì gba gbogbo ìlú u rẹ̀ là pẹ̀lú ọgbọ́n-ọn rẹ̀ Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó rántí ọkùnrin talákà náà Nítorí náà mo ṣọ wí pé Ọgbọ́n dára ju agbára Ṣùgbọ́n a kẹ́gàn ọgbọ́n ọkùnrin talákà náà, wọn kò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ọlọgbọ́n ènìyàn a máa wà ní ìmú ṣe ju igbe òmùgọ̀ alákòóso lọ Ọgbọ́n dára ju ohun—èlò ogun lọ, ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ kan a máa ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́ Ìbùkún Ti Ẹ̀mí Mímọ́ Nínú Kírísítì Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì Jésù Kírísítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Éfésù, àti sí àwọn olótìtọ́ nínú Kírísíti Jésù Oore ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jésù Kírísítì Olúwa Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jésù Kírísítì Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kírísítì Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ Nínú ìfẹ́ ni Ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jésù Kírísítì fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀ fún ìyìn ogo oore ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí Ó ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀ Nínú rẹ̀ ni àwa ni ìràpadà wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run èyí tí ó ya lù wá pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye, Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mímọ̀ fún wa, gẹ́gẹ́ bí idùnnù rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kírísítì, èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ orí kan àní Kírísítì Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́hìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀, kí àwa tí ó jẹ́ àkóso ìrètí nínú Kírísítì lè jásí ìyìn ògo rẹ̀ Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kírísítì nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìyìnrere ìgbàlà yin Lẹ́yìn tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a lù yín ní òǹtẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀, èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àsansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ìní Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀ Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúro ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàárin yín nínú Jésù Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi Mo sì ń bèèrè nígbàgbogbo pé kí Ọlọ́run Jésù Kírísítì Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọ̀gbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ọ́ sí i Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkan yín lè mọ́lẹ̀ kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìreti ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́ àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́ Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ agbára rẹ̀, èyí tí ó fi sínú Kírísítì, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jòkòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run Ó gbé e ga ju gbogbo ìsàkóso, àti àṣẹ, àti agbára, àti ilẹ̀ ọba àti gbogbo àpèlé orúkọ tí a lè ti fún mi, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ èyí tí i ṣe ara rẹ̀, ẹ̀kún ẹni tí o kún ohun gbogbo ní gbogbo ọ̀nà Ìsọdààyè nínú Kírísítì Ní ti ẹ̀yin, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè, nígbà ti ẹ̀yin ti kú nítorí ìrékọjá àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, nínú èyí tí ẹ̀yin ti gbé rí àní bí ipá ti ayé yìí, gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ agbára ojú ọ̀run, ẹ̀mí tí n ṣiṣẹ́ ni isinsìn yìí nínú àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn Nínú àwọn ẹni tí gbogbo wa pẹ̀lú ti wà rí nínú ìfẹ́kúfẹ ara wa, a ń mú ìfẹ́ ara àti ti inú ṣẹ, àti nípa ẹ̀dá àwa sì ti jẹ́ ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìyókù pẹ̀lú Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe ọlọ́rọ̀ ni àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa, nígbà tí àwa tilẹ̀ ti kú nítorí ìrékọjá wa, ó sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kírísítì oore ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là Ọlọ́run sì ti jí wa dìde pẹ̀lú Kírísítì, ó sì ti mú wa jókòó pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run nínú Kírísítì Jésù Pé ni gbogbo ìgbà tí ń bọ̀ kí ó bà á lè fi ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí o pọ̀ rékọjá hàn fún wa nínú ìṣehun rẹ̀ sì wà nínú Kírísítì Jésù Nítorí oore ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́ àti èyí yìí kì í ṣe ti láti ọ́dọ̀ ẹ̀yin fúnra yín ẹ̀bùn Ọlọ́run ni Kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kírísítì Jésù fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèṣè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ aláìkọlà nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní Akọlà ti a fi ọwọ́ ṣe ni ara ń pè ní Aláìkọlà ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kírísítì, ẹ jẹ́ àjèjì sí àǹfàní àwọn ọlọ̀tọ̀ Ísírẹ́lì, àti àlejò sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kírísítì Jésù ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kírísítì Nítorí oun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórira èyí tí ń bẹ láàrin yín Nípa pípa àṣẹ, àwọn òfin àti ìlànà gbogbo rẹ̀ nínú ara rẹ̀ Àfojúsùn rẹ̀ i kí ó le dá ọkùnrin tuntun kan nínú ara rẹ̀ nínú àwọn méjèèjì, kí àlááfíà kí ó lè wà nípa èyí àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú nípa èyí tí yóò fi pa ìsòtá náà run Ó sì ti wá ó sì ti wàásù àlàáfíà fún ẹ̀yin tí o jìnnà réré, àti àlááfíà fún àwọn tí o súnmọ́ tòòsí Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan Ǹjẹ́ nítorí náà ẹ̀yin kì í ṣe àlejò àti àtìpó mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ara ilé Ọlọ́run a sì ń gbé yín ró lórí ìpilẹ̀ àwọn àpostélì, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jésù Kírísítì fúnra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ sọ̀kan tí ó sì ń dàgbà sókè láti di tẹ́ḿpìlì mímọ́ kan nínú Olúwa Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pọ̀ pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀ Pọ́ọ̀lù Jẹ́ Oníwàásù Sí Àwọn aláìkọlà Nítorí èyí náà ni èmi Pọ́ọ̀lù ṣe di òǹdè Jésù Kírísítì nítorí ẹ̀yin aláìkọlà, Bí ẹ̀yin bá tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fifún mi fún yín Bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni sókí, Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kírísítì Èyí tí a kò í tíì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn àpostélì rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí Pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kírísítì Jésù nípa ìyìn rere Ìránṣẹ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fifún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀ Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídi ọ̀rọ̀ Kírísítì fún àwọn aláìkọlà Àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ayébáyé nínú Ọlọ́run, ẹni tí o dá ohun gbogbo nípa Jésù Kírísítì Kí a bà á lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onirúuru ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àtayébáyé tí ó ti pinnu nínú Kírísítì Jésù Olúwa wa Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀ Nítorí náà mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, tíi ṣe ògo yín Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eekún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ mú ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ Kí Kírísítì lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́ pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́ Kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga náàìfẹ́ Kírísítì jẹ́ Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kírísitì yìí tí o ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kún Ọlọ́run kún yín Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kírísítì Jésù títí ìrandíran gbogbo, ayé àìnípẹ̀kun, Àmí Ìṣọ̀kan Nínú Ara Jésù Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí Pẹ̀lu ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà Ara kan ni ń bẹ, ati Ẹ̀mí kan, àní bí a ti pè yín sínú ìrètí kan nígbà tí a pè yín Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìtẹ̀bọmi kan Ọlọ́run kan ati Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó se olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú gbogbo Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ni a fi oore ọ̀fẹ́ fun gẹ́gẹ́ bi òṣùwọ̀n ẹ̀bùn Kírísítì Nitorí náà a wí pé Nígbà tí ó gókè lọ sí ibi gíga, ó di ìgbékùn ni ìgbékùn, ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn Ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí àpósítélì àti àwọn mìíràn bí i wòlíì àti àwọn mìíràn bí ajínyìnrere, àti àwọn mìíràn bí Olùṣọ́ àgàntàn àti olùkọ́ni Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ fun iṣẹ́ ìráńṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kírísítì Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kírísítì Kí àwa má ṣe jẹ́ èwe mọ́, tí a ń fi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá tì sẹ́yìn, tí a sì fi ń gbá kiri, nípa ìtànjẹ ènìyàn, nípa àrékérekè fun ọgbọ́nkọ́gbọ́n àti mú ni sìnà Ṣùgbọ́n ká a máa sọ òtítọ́ ní ìfẹ́, kí a lè máa dàgbàsókè nínú rẹ̀ ní ohun gbogbo ẹni tí i ṣe orí, àní Kírísítì Láti ọ̀dọ̀ ẹni ti ara náà tí a ń so ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń fi ara mọ́ra, nípaṣẹ̀ oríkèé kọ̀ọ̀kan tí a ti pèsè, nígbà tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ dáradára, yóò mú ara dàgbà, yóò sì gbé ara òun tìkárárẹ̀ dìde nínú ìfẹ́ Ǹjẹ́ èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí nínú Olúwa pé, láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹ̀yin má ṣe rìn mọ́, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà ti ń rìn nínú ìrònú asán wọn Òye àwọn ẹni tí ó ṣókùnkùn, àwọn tí ó sì di àjèjì sí ìwà-bí-Ọlọ́run nítorí àìmọ̀ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí lílè ọkàn wọn Àwọn ẹni tí ọkàn wọn le rékọjá, tí wọ́n sì ti fi ara wọn fún wọ̀bìà, láti máa fi ìwọ́ra ṣiṣẹ́ ìwà èérí gbogbo Ṣùgbọ́n a kò fi Kírísítì kọ́ yín bẹ́ẹ̀ Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí otítọ́ ti ń bẹ nínú Jésù Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ogbologbo ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ̀ bí ìfẹ́kúfẹ́ ẹ̀tàn Kí ẹ sì di titun ni ẹ̀mí inú yín Kí ẹ sì gbé ọkùnrin titun wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́ Nítorí náà ẹ fi èké ṣiṣe sílẹ̀, ki olúkúlùkù yín máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara ọmọnìkejì wa ni àwá jẹ́ Nínú ìbínú yín, ẹ máa ṣe ṣẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí òòrùn wọ̀ bá ìbínú yín Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè fún Èṣù Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́ ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dara, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdibàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí ti o dara fún ẹ̀kọ́, kí ó lè máa fi oore ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́ Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àránkan Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkéjì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríji ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kírísítì ti dáríjì yín Àwọn Aya àti Ọkọ Nítorí náà, ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọ́run bí àwọn olùfẹ́ ọmọ, ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kírísítì pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà-èérì, tàbi ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàárin yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mimọ Ìbáà ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìsọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́ ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́ Nítorí ẹ̀yín mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tabì wọ̀bìà, tí yóò ni ìní kán ni ìjọ́bà Kírísítì àti Ọlọ́run Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fí ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ nítorí nípaṣẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n níṣinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa Ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí Nítorí ìtìjú tilẹ̀ ni láti máa sọ̀rọ̀ nǹkán wọ̀n-ọn-nì tí àwọn aláìgbọ́ràn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀ Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn nítorí ohunkóhun tí ó bá fí nǹkàn hàn, ìmọ́lẹ̀ ni Nítórí náà ni ó ṣẹ́ wí pé, Jí, ìwọ̀ ẹní tí ó sun, Sí jíǹdè kúrò nínú òkú Kírísítì yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀ Nítorí náà ẹ kíyésì láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n Ẹ máa ra ìgbà padá, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́ Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòyé ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurúdu wà ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Sáàmù, àti orin ìyìn, atí orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrìn dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jésù Kírísítì Olúwa wá Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run Ẹ̀yín aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kírísítì tí i ṣe orí ìjọ, tí ó ń ṣe ara rẹ̀, oún si ni Olugbálá rẹ̀ Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ijọ tí i tẹríba fún Kírísítì, bẹ́ẹ̀ sì ní kì àwọn aya máa ṣe sí ọkọ wọn ní ohun gbogbo Ẹ̀yín ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kírísítì tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fí ara rẹ̀ fún-un Kí òun lè sọ ọ́ dí mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fí ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí Kí òun lé mú ún wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó lógó láìní àbàwọ́n, tàbí àlébù kan, tàbí irú nǹkán bá-wọ̀n-ọn-nì ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ mímọ́ àti aláìní àbùkù Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kóríra ara rẹ̀ bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa sìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kírísítì sì ti ń ṣe sí ìjọ Nítorí pé àwa ni ẹ̀yà ara rẹ̀, àti tí ẹran ara rẹ̀, atí egúngún ara rẹ̀ Nítorí èyí ní ọkùnrin yóò ṣe fí Baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì á sí dí ara kán Àṣírí ńlá ní èyí ṣùgbọ́n èmí ń sọ nípá ti Kírísítì àti tí ìjọ Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín fẹ́ràn aya rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀ kí aya kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ Àwọn Ọmọ Àti Àwọn Òbí Ẹ̀yín ọmọ, ẹ máa gbọ tí àwọn òbí i yín nínú Olúwa nítorí pé èyí ní ó tọ́ Bọ̀wọ̀ fún bábá àtí ìyá rẹ èyí tí í ṣe ofín kìn-ín-ní pẹ̀lú ilérí, Kí ó lé dára fún ọ, àti kí ìwọ lè wà pẹ́ ní ayé Àti ẹyín baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àtí ìkìlọ̀ Olúwa Ẹ̀yín ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹ máa gbọ́ ti àwọn olúwa yín nípá ti ara, pẹ̀lú ìbẹ̀rù àtí ìwárìrì, ní òtítọ́ ọkàn yín, bí ẹni pé sí Kírísítì Gbọ́ ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu kì í ṣe láti rí ojúrere wọn nígbà tí ojú wọn bá ń bẹ lára rẹ, ṣùgbọ́n bí ẹrú Kírísítì, ní síṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láti ọkàn rẹ Ẹ máa fí inú rere sìn bí sí Olúwa, kì í sí ṣe sí ènìyàn Bí ẹ̀yín ti mọ̀ pé ohun rere tí olúkúlùkù bá ṣe òun náà ní yóò sí gbà padá lọ́dọ̀ Olúwa, ìbá à ṣe ẹrú, tàbí òmìnira Àti ẹ̀yín ọ̀gá, ẹ máa ṣe ohun kan náà sí wọn, ẹ máa dín ìbẹ̀rù yín kù bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé olúwa ẹ̀yin tìkárayín ń bẹ ní ọ̀run kò sì sí ojúṣáájú ènìyàn lọ́dọ̀ rẹ̀ Ní àkótan, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀ Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yín lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè Èṣù Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara ní awá ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyé, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àtí àwọn ẹmí búburú ní ojú ọrun Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yín lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra Tí ẹ sì ti fí ìmúrà ìyìn rere àlàáfíà wọ ẹṣẹ̀ yín ní bàtà Ní àfikún, ẹ mú apata ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yín lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ni kí ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo nínú Ẹ̀mí, kí ẹ sì máa ṣọ́ra sí i nínú ìdúrósinsin gbogbo àti ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ènìyàn mímọ́ Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún mí pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè fún mí ní ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí emí lè máa fì ìgbóyà sọ àwọn ohun ìjìnlẹ ìyìn rere náà Nítorí èyí tí èmí jẹ́ ikọ̀ nínú ẹ̀wọ̀n kí èmi lè máa fi ìgbóyà sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mí láti máa sọ Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè mọ̀ bí nǹkán ti rí fún mí, bí mo tí ń ṣe sí Tíkíkù, arákùnrin olùfẹ́ àti ìránṣẹ́ olóòótọ́ nínú Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dí mímọ̀ fún yín Ẹni tí mo rán sí yín nítorí èyí náà, kí ẹ lè mọ̀ bí a tí wà, kì òun lè tu ọkàn yín nínú Àlàáfíà fún àwọn ará, àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, làti ọdọ Ọlọ́run Baba wà, àti Olúwa wà Jésù Kírísítì Kí oore ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì ni àìṣẹ̀tàn A Rọ Ayaba Fásítì Lóyè Èyí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà Sérísésì, tí ó jọba lórí ẹ̀tàdínláàdóje ìletò bẹ̀rẹ̀ láti Índíà títí ó fi dé Etiópíà Ní àkókò ìgbà náà ọba Ṣérísésì ń ṣe ìjọba ní orí ìtẹ́ ẹ rẹ̀ ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúsà, Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè Àwọn olórí olóógun láti Páṣíà àti Médíà, àwọn ọmọ aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọlá ńlá a rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí kọjá, ọba se àsè fún ọjọ́ méje, nínú ọgbà tí ó wà nínú àgbàlá ààfin ọba, gbogbo ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni tí ó lọ́lá jùlọ, tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ ti Súsà Ọgbà náà ní aṣọ fèrèsé funfun àti aláwọ̀ òféfèé Àwọn okùn tí a fi aṣọ aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ elésé àlùkò rán ni a fi ta á mọ́ òrùka fàdákà lára àwọn òpó mábù Àwọn ibùṣùn tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe wà níbi pèpéle òkúta tí a fi ń tẹ́lẹ̀ ilé tí ó jẹ́ mábù, píálì àti òkúta olówó iyebíye mìíràn Kọ́ọ̀bù wúrà onídìí-odó ni a fi ń bu wáìnì fún wọn mu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì yàtọ̀ sí èkejì, wáìnì ọba pọ̀ púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe lawọ́ sí Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba a fi ààyè gba àlejò kọ̀ọ̀kan láti mu tó bí ó bá ti fẹ́, nítorí ọba ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ti ń bu wáìnì láti bù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ṣe béèrè fún mọ Ayaba Fásítì náà ṣe àṣè fún àwọn obìnrin ní ààfin ọba Ṣérísésì, Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì mú inú ọba dùn, ó pàṣẹ fún Méhúmínì, Bísítà, Hábónà, Bígítà àti Ábágítà, Ṣétarì àti Kákásì, àwọn ìwẹ̀fà méje tí ń jíṣẹ́ fún un Kí wọn mú ayaba Fásítì wá ṣíwájúu rẹ̀, ti òun ti adé ọba rẹ̀, kí ó lè wá fi ẹwà rẹ̀ hàn àwọn ènìyàn àti àwọn ọlọ́lá, nítorí tí ó rẹwà Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Fásítì kọ̀ láti wá Nígbà náà ni ọba bínú gidgidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní ìgbà gbogbo, ọba máa ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ìmọ̀ òfin àti ìdájọ́, ó sọ ọ́ fún àwọn amòye tí wọ́n mòye àkókò, àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọba àwọn wọ̀nyí ni Káríṣénà, Ṣétarì, Ádímátà, Tárísísì, Mérésì, Márísénà àtí Mémúkánì, àwọn ọlọ́lá méje ti Páṣíà àti Médíà tí wọ́n ṣe pàtàkì sí ọba, wọ́n sì tún wà ní ibi gíga ní ìjọba Ó béèrè pé, Kí ni a lè ṣe sí ayaba Fásítì gẹ́gẹ́ bí òfin Nítorí kò tẹríba fún àṣẹ ọba Ṣérísésì tí àwọn ìwẹ̀fà ọba sọ fún un Mémúkánì sì dáhùn níwájú ọba àti àwọn ọlọ́lá pé, Ayaba Fásítì ti ṣe búburú, kì í ṣe sí ọba nìkan Ṣùgbọ́n sí gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo agbégbé ilẹ̀ ọba Ṣérísésì Nítorí ìwà ayaba yìí yóò tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn obínrin, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ wọn yóò di gígàn lójúu wọn, wọn yóò sì sọ pé, ọba Ṣérísésì pàṣẹ̀ pé kí á mú ayaba Fásítì wá ṣíwájú òun, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti wá Ní ọjọ́ yìí gan-an ni àwọn ọlọ́lá obinrin Páṣíà àti ti Médíánì tí wọ́n ti gbọ́ nípa ìwà ayaba wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba bákan náà Àfojúdi àti àìnírẹ́pọ̀ tí kò lópin yóò wà Nítorí náà, bí ó bá tọ́ lójú ọba, jẹ́ kí ó gbé àṣẹ ọba jáde, kí ó sì jẹ́ kí ó wà ní àkọsílẹ̀ pẹ̀lú òfin Pásíà àti Médíánì, èyí tí kò le é parẹ́, pé kí Fásítì kí ó má ṣe wá ṣíwájú ọba Ṣérísésì Kí ọba sì fi oyè ayaba rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó ṣàn jù ú lọ Nígbà náà tí a bá kéde òfin tí ọba ṣe ká gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin ni yóò bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó kéré títí dé ọ̀dọ̀ ẹni ńlá Ìmọ̀ràn yìí sì tẹ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ́rùn, nítorí náà ọba ṣe gẹ́gẹ́ bí Mémúkánì ṣé sọ Ó kọ̀wé ránṣẹ́ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ọba rẹ̀, ó kọ̀wé sí ìgbéríko kọ̀ọ̀kan ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, Ó tẹnumọ́ ọ ní èdè oníkálùkù pé kí olúkálùkù ọkùnrin máa ṣàkóso ilé e rẹ̀ Títóbi Módékáì Ọba Ṣéríṣésì sì fi owó ọba lélẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ọba, dé erékùṣù òkun Àti gbogbo ìṣe agbára àti títóbi rẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìròyìn títóbi Módékáì ní èyí tí ọba ti gbé e ga, kò ha wà nínú àkọsílẹ̀ ìwé ọdọọdún ọba ti Médíà àti ti Páṣíà Módékáì ará Júù ni ó jẹ́ igbá kejì ọba Ṣéríṣésì, ó tóbi láàrin àwọn Júù, ó sì jẹ́ ẹni iyì lọ́dọ̀ àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, nítorí tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ire àwọn ènìyàn an rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ fún àlàáfíà gbogbo àwọn Júù Éṣítà Di Ayaba Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Ṣérísésì ọba sì dáwọ́ ìbínú un rẹ̀ dúró, ó rántí i Fásítì àti ohun tí ó ti ṣe àti àṣẹ tí ó pa nípa tirẹ̀ Nígbà naà ni ìránṣẹ́ ọba tí ó wà ní ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀ wí pé, jẹ́ kí a wá ọmọbìnrin arẹwà tí kòì mọ ọkùnrin rí fún ọba Àti pé kí ọba kí ó yan àwọn aláṣẹ ní gbogbo agbégbé ilẹ̀ ọba láti kó gbogbo àwọn arẹwà ọmọbìnrin wọ̀nyí jọ sí ilé àwọn obìnrin ní ilé ìṣọ́ Ṣúṣà Kí a kó wọn fún ìtọ́jú Hégáì, ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ó ṣe olùtọ́jú àwọn obìnrin kí a ṣe ìtọ́jú u wọn dáradára Nígbà naà kí ọmọbìnrin tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn kí ó jẹ́ ayaba dípò Fásítì Ìmọ̀ràn yìí tẹ́ ọba lọ́rùn, ó sì tẹ̀lé e Ó sì ṣe ní ìgbà náà ará a Júù kan wà ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúsà, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Módékáì ọmọ Jáárì, ọmọ Símù, ọmọ Kúsì, ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Ẹni tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì ti gbé lọ sí ìgbèkùn láti Jérúsálẹ́mù, lára àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn pẹ̀lú ọba Jéóhákímù ọba Júdà Módékáì ní arákùnrin kan ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hádásà, ẹni tí ó tọ́ dàgbà nítorí tí kò ní bàbá bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìyá Obìnrin yìí, ẹni tí a tún mọ̀ sí Ẹ́sítà, ó dára ó sì lẹ́wà, Módékáì mú u gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ nígbà tí bàbá àti ìyá rẹ̀ ti kú Nígbà tí a ti kéde òfin àti àṣẹ ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin ni a kó wá sí ilé ti ìṣọ́ Ṣúsà, sí abẹ́ ìtọ́jú Hégáì A sì mú Ẹ́sítà náà wá sí ààfin ọba pẹ̀lú, a fà á lé Hégáì lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó ilé àwọn obìnrin Ọmọbìnrin náà sì wù ú, ó sì rí ojú rere rẹ̀, lẹ́ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ ó pèṣè àwọn ohun tí ó dára àti oúnjẹ pàtàkì fún-un Ó sì yan àwọn ìránṣẹ́bìnrin wúndíá méje láti ààfin ọba òun àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà lọ sí ibi tí ó dára jù nínú ilé àwọn obìnrin Ẹ́sítà kò tíì sọ nípa àwọn ènìyàn àti ìdílé e rẹ̀, nítorí Módékáì ti pàṣẹ fún-un pé kí ó má ṣe ṣọọ́ Ní ojoojúmọ́ ni Módékáì máa ń rìn ní iwájú ilé àwọn obìnrin láti wo bí Ẹ́sítà ṣe wà àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i Kí àkókò tó tó fún obìnrin kọ̀ọ̀kan láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ṣérísésì, ó ní láti lo ohun èlò tí ń mú ara lẹ́wà tí a yàn fún àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, yóò lo òróró òjía fún oṣù mẹ́fà, yóò sì lo ohun èlò olóòrùn dídùn tùràrí àti ìpara fún oṣù mẹ́fà pẹ̀lú Báyìí ni yóò ṣe lọ ṣíwájú ọba ohunkóhun tí ó bá béèrè ni wọ́n fi fún-un láti inú ilé àwọn obìnrin lọ sí ààfin ọba Ní alẹ́ ni yóò lọ ṣíbẹ̀, tí ó bá sì di òwúrọ̀ yóò padà sí ilé kejì nínú ilé àwọn obìnrin ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣáásígásì ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó máa ń ṣe ìtọ́jú àwọn àlè Òun kò ní lọ sí ọ̀dọ̀ ọba mọ́ àyààfi tí inú ọba bá dùn síi, tí ó sì ránṣẹ́ pé ó ní orúkọ obìnrin Nígbà tí ó kan Ẹ́sítà láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọn kò bèrè fún ohunkóhun ju èyí tí Hégáì, ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ilé àwọn obìnrin sọ pé kí ó ṣe lọ Ẹ́sítà sì rí ojú rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí ó rí i A mú Ésítà lọ síwájú ọba Ṣéríṣésì ní ibùgbé ọba ní oṣù kẹ́wàá, tí ó jẹ́ oṣù Tébétì, ní ọdún kéje ìjọba rẹ̀ Ésítà sì wu ọba ju àwọn obìnrin tó kù lọ, Ó sì rí ojú rere àti oore ọ̀fẹ́ gbà ju ti àwọn wúndíá tó kù lọ Nítorí náà ó fi adé ọba dé e ní orí ó sì fi ṣe ayaba dípò Fásítì Ọba sì se àsè ńlá, àsè Ésítà, fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè e rẹ̀ Ó sì kéde ìsinmi jákèjádò ìgbéríko ó sì pín ẹ̀bùn fún wọn pẹ̀lú bí ọba ṣe lawọ́ tó Nígbà tí àwọn wúndíá tún péjọ ní ìgbà kejì, Módékáì jókòó sí ẹnu ọ̀nà ọbà Ṣùgbọ́n Ẹ́sítà pa àṣírí ìdílé e rẹ̀ àti ibi tí ó ti wá mọ́gẹ́gẹ́ bí Módékáì ṣe sọ fún un pé kí ó ṣe, nítorí tí ó ń tèlé àṣẹ tí Módékáì fún-un gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń ṣe nígbà tí ó wà ní ọ̀dọ̀ Módékáì Ní àsìkò tí Módékáì jókòó sí ẹnu ọ̀nà ọba, Bígítanà àti Térésì, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n máa ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà, wọ́n bínú, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa ọba Sérísésì Ṣùgbọ́n Módékáì sì mọ̀ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sọ̀ fún ayaba Ẹ́sítà, Ẹ́sítà sì sọ fún ọba, wọ́n sì fi ọlá fún Módékáì Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀rọ̀ náà tí ó sì já sí òtítọ́, a sì ṣo àwọn ìjòyè méjèèjì náà kọ́ Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a kọ sínú ìwé ìtàn ní iwáju ọba Ọ̀tẹ̀ Hámánì Láti Pa Àwọn Júù Run Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ọba Ṣérísésì dá Hámánì ọmọ Hámádátà, ará a Ágágì lọ́lá, ọba gbé e ga, ó si fún un ní àga ọlá tí ó ju ti gbogbo àwọn ọlọ́lá tó kù lọ Gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà ọba wọn kúnlẹ̀ wọ́n sì fi ọlá fun Hámánì, nítorí ọba ti pàṣẹ èyí nípa tirẹ̀ Ṣùgbọ́n Modékáì kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún-un Nígbà náà ni àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà béèrè lọ́wọ́ Módékáì pé, È éṣe tí ìwọ kò ṣe pa àṣẹ ọba mọ́ Ní ojoojúmọ́ ni wọ́n máa n sọ fún-un ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ Nítorí náà, wọ́n sọ fún Hámánì nípa rẹ̀ láti wòó bóyá ó lè gba irú ìwà tí Módékáì ń hù yìí, nítorí tí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun Nígbà tí Hámánì ríi pé Módékáì kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú Síbẹ̀ kò mọ irú ènìyàn tí Módékáì jẹ́, ó kẹ́gàn àti pa Módékáì nìkan Dípò bẹ́ẹ̀ Hámánì ń wá láti pa gbogbo ènìyàn Módékáì run, àwọn Júù jákèjádò gbogbo ìjọba Ṣérísésì Ní ọdún kejìlá ọba Ṣérísésì, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù nísánì, wọ́n da Púrì ní iwájú Hámánì láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Ádárì Nígbà náà ni Hámánì sọ fún ọba Ṣérísésì pé, Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fánká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tó kù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́ èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀ Tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, kí a gbé òfin kan jáde tí yóò pa wọ́n run, èmi yóò sì fi ẹgbàarùn-ún talẹ́ńtì fàdákà sínú ìṣúra ọba fún àwọn ọkùnrin tí wọn ṣe iṣẹ́ náà Nítorí náà ọba sì bọ́ òrùka dídán tí ó wà ní ìka rẹ̀ ó sì fi fún Hámánì ọmọ Hámédátà, ará Ágágì, ọ̀ta àwọn Júù Ọba sọ fún Hámánì pé, pa owó náà mọ́ kí o sì ṣe ohun tí ó wù ọ́ fún àwọn ènìyàn náà Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀ wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hámánì ti pa láṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn A kọ èyí ní orúkọ ọba Ṣérísésì fúnra rẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀ A sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìgbèríko pẹ̀lú àṣẹ láti parun, láti pa gbogbo àwọn Júù èwe àti àgbà, obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́ẹ́wẹ́—ní ọjọ́ kan kí wọn sì parẹ́, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Ádárì kí a sì kó àwọn ohun ìní in wọn Kí ẹ mú àdàkọ kan ìwé náà kí a tẹ̀ẹ́ jáde bí òfin ní gbogbo ìgbéríko kí ó sì di mímọ̀ fún àwọn ènìyàn ìlú nítorí kí wọ́n le múra fún ọjọ́ náà Àwọn ìránṣẹ́ náà sì jáde, wọ́n tẹ̀síwájú nípa àṣẹ ọba, ìkéde náà sì jáde ní ìlé ìsọ́ ti Ṣúsà Ọba àti Hámánì jókòó wọ́n ń mu, ṣùgbọ́n ìlú Ṣúsà wà nínú ìdààmú Módékáì Rọ Ẹ́sítà Láti Ràn Àwọn Júù Lọ́wọ́ Nígbà tí Módékáì gbọ́ gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì fi eérú kunra, ó jáde lọ sí inú ìlú ó kígbe ṣókè ó sì sunkún kíkorò Ṣùgbọ́n ó lọ sí ẹnu ọ̀nà ọba nìkan, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀ tì a gbà láàyè láti wọ ibẹ̀ Ní gbogbo ìgbèríko tí ikú àti àṣẹ ọba dé, ọ̀fọ̀ ǹlá dé bá àwọn Júù, pẹ̀lú ààwẹ̀, ẹkún àti ìpohùn réré ẹkún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà ninú aṣọ ọ̀fọ̀ tí wọ́n fi eérú kúnra Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ìwẹ̀fà Ẹ́sítà wá, wọ́n sọ nípa Módékáì fún-un, ó sì wà nínú ìbànújẹ́ ńlá Ó fi aṣọ ránṣẹ́ síi kí ó wọ̀ ọ́ dípò aṣọ ọ̀fọ̀ tí ó wọ̀, ṣùgbọ́n òun kò gbà wọ́n Nígbà náà ni Ẹ́sítà pe Hátakì, ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà ọba tí a yàn láti máa jíṣẹ́ fún-un, ó pàṣẹ fún un pé kí ó béèrè ohun tí ó ń dààmú Módékáì àti ohun tí ó ṣe é Bẹ́ẹ̀ ni Hátakì jáde lọ bá Módékáì ní ìta gbangba ìlú niwájú ẹnu ọ̀nà ọba Módékáì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún-un, papọ̀ pẹ̀lú iye owó tí Hámánì ti ṣe ipinnu láti san sínú àpò ìṣúra ọba fún ìparun àwọn Júù Ó sì tún fún un ní ọ̀kan lára ìwé tí ó gbé jáde fún ìparun àwọn, èyí tí a tẹ̀ jáde ní Ṣúṣà, láti fi han Ésítà kí ó sì ṣe àlàyé e rẹ̀ fún-un, ó sì sọ fún-un pé kí ó bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ ṣíwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú, kí ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn an rẹ̀ Hátakì padà ó sì lọ ṣàlàyé fún Ẹ́sítà ohun tí Módékáì sọ Nígbà náà ni Ésítà pàṣẹ fún un pé kí ó sọ fún Módékáì, Gbogbo àwọn ìjòyè ọba àti àwọn ènìyàn agbègbè ìjọba rẹ̀ mọ̀ wí pé fún ẹnikẹ́ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tàbí tí ó bá bá ọba sọ̀rọ̀ láì jẹ́ pé a ránsẹ́ pèé kíkú ni yóò kú Ohun kan tí ó le yẹ èyí ni pé, kí ọba na ọ̀pá a góòlùu rẹ̀ síi kí ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí Ṣùgbọ́n, ọgbọ̀n ọjọ́ ti kọjá tí a ti pè mí láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Nígbà tí a sọ ọ̀rọ̀ Ẹ́sítà fún Módékáì, Ó sì rán ìdáhùn yí sí i pé Má ṣe rò pé nítorí pé ìwọ wà nílé ọba ìwọ nìkan lè yọ láàrin gbogbo àwọn Júù Nítorí bí ìwọ bá dákẹ́ ní àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ fún àwọn Júù yóò dìde láti ibòmíràn, Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ìdílée bàbá à rẹ yóò ṣègbé Taa ni ó mọ̀ wí pé nítorí irú àkókò yìí ni o ṣe wà ní ipò ayaba Nígbà náà ni Ẹ́sítà rán iṣẹ́ yìí sí Módékáì Lọ, kí o kó gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúsà jọ, kí ẹ sì gbààwẹ̀ fún mi Ẹ má ṣe jẹun tàbí omi fún ọjọ́ mẹ́ta, ní òru àti ní ọ̀ṣán Èmi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi náà yóò gbààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti ṣe Nígbà tí ẹ bá ṣe èyí, èmi yóò tọ ọba lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin Bí mo bá sì ṣègbé, mo ṣègbé Bẹ́ẹ̀ ni Módékáì lọ, ó sì sọ gbogbo ohun tí Ẹ́sítà pa láṣẹ fún-un Ẹ̀bẹ̀ Ẹ́sítà Sí Ọba Ní ọjọ́ kẹta Ẹ́sítà wọ aṣọ ayaba rẹ̀ ó sì dúró sí inú àgbàlá ààfin, ní iwájúu gbọ̀ngàn ọba, ọba Jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ nínú un gbọ̀ngàn, ó kọjú sí ẹnu ọ̀nà ìta Nígbà tí ó rí ayaba Ẹ́sítà tí ó dúró nínú àgbàlá, inú un rẹ̀ yọ́ síi, ó sì na ọ̀pá aládé wúrà ọwọ́ọ rẹ̀ sí i Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ́sítà ṣe ṣún mọ́ ọn ó sì fi ọwọ́ kan orí ọ̀pá náà Nígbà náà ni ọba béèrè pé, kí ni ó dé, ayaba Ẹ́sítà Kí ni o fẹ́ Bí ó tilẹ̀ ṣe títí dé ìdajìn mi ìjọba àní, a ó fi fún ọ Ẹ́sítà sì dáhùn pé, Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, jẹ́ kí ọba, pẹ̀lúu Hámánì, wá lónìí sí ibi àṣè tí èmi ti pèṣè fún-un Ọba sì wí pé, ẹ mú Hámánì wá kíákíá, nítorí kí a lè ṣe ohun tí Ẹ́sítà béèrè fún un Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti Hámánì lọ sí ibi àsè tí Ẹ́sítà ti pèsè Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì, ọba tún béèrè lọ́wọ́ Ésítà, Báyìí pẹ́ kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ A ó sì fi fún ọ Kí ni ìwọ ń béèrè fún Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọbaa mi, a ó fi fún ọ Ẹ́sítà sì dáhùn, Ẹ̀bẹ̀ mi àti ìbéèrè mi ni èyí Bí ọba bá fi ojú rere rẹ̀ fún mi, tí ó bá sì tẹ́ ọba lọ́rùn láti gba ẹ̀bẹ̀ mi àti láti mú ìbéèrè mi ṣẹ, jẹ́ kí ọba àti Hámánì wá ní ọ̀la sí ibi àṣè tí èmi yóò pèṣè fún wọn Nígbà náà ni èmi yóò dáhùn ìbéèrè ọba Hámánì jáde lọ ní ọjọ́ náà pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí Módékáì ní ẹnu ọ̀nà ọba, ó wòye pé kò dìde tàbí kí ó bẹ̀rù ní iwájú oun, inú bí i gidigidi sí Módékáì Ṣùgbọ́n, Hámánì kó ara rẹ̀ ní ìjánu, ó lọ sí ilé Ó pe àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀ jọ àti Sérésì ìyàwóo rẹ̀, Hámánì gbéraga sí wọn nípa títóbi ọ̀rọ̀ rẹ̀, púpọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ọ̀nà tí ọba ti bu ọla fún-un àti bí ó ṣe gbé e ga ju àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè tó kù lọ Hámánì tún fi kún-un pé, Kìí ṣe èyí nìkan Èmi nìkan ni ayaba Ẹ́sítà pè láti sin ọba wá sí ibi àsè tí ó sè Bákan náà, ó sì tún ti pè mí pẹ̀lú ọba ní ọ̀la Ṣùgbọ́n gbogbo èyí kò ì tíì tẹ́ mi lọ́rùn níwọ̀n ìgbà tí mo bá sì ń rí Módékáì aráa Júù yẹn tí ó ń jòkòó lẹ́nu ọ̀nà ọba Ìyàwó rẹ̀ Ṣérésì àti àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀ wí fún-un pé, Ri igi kan, kí ó ga tó ìwọ̀n míta mẹ́ta-lélógún, kí o sì sọ fún ọba ní òwúrọ̀ ọ̀la kí ó gbé Módékáì rọ̀ sórí i rẹ̀ Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọba lọ sí ibi àṣè pẹ̀lú ayọ̀ Èrò yí dùn mọ́ Hámánì nínú, ó sì ri igi náà Ọba Bu Ọlá Fún Módékáì Ní òru ọjọ́ náà ọba kò le è ṣùn nítorí náà, ó pàṣẹ kí wọn mú ìwé ìrántí wá, àkọsílẹ̀ ìjọba rẹ̀, wọ́n mú un wá wọ́n sì kàá síi létí Wọ́n rí àkọsílẹ̀ níbẹ̀ pé Módékáì tí sọ àṣírí Bígítanà àti Térésì, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà, tí wọ́n ń gbérò láti pa ọba Ṣérísésì Ọba béèrè pé, Kí ni ọlá àti iyì tí Módékáì ti gbà fún èyí Àwọn ìránṣẹ́ẹ rẹ̀ sì dáhùn pé, Kò tíì sí ohun tí a ṣe fún-un Ọba wí pé, Taa ni ó wà nínú àgbàlá Nísinsin yìí Hámánì ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ àgbàlá ìta ààfin ni láti sọ fún ọba nípa ṣíṣo Módékáì lórí igi tí ó ti rì fún-un Àwọn ìránṣẹ́ẹ rẹ̀ sì dáhùn pé, Hámánì ni ó wà níbẹ̀ ó dúró sí inú àgbàlá Ọba pàṣẹ pé, Ẹ mú un wọlé wá Nígbà tí Hámánì wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ọ rẹ̀ pé, Kí ni kí a ṣe fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti bu ọlá fún Nísinsìnyìí Hámánì sì ro èyí fúnra rẹ̀ pé, Taa ni ó wà níbẹ̀ tí ọba fẹ́ dá lọ́lá ju èmi lọ Nítorí náà ó dá ọba lóhùn pé, Fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, jẹ́ kí wọn kí ó mú aṣọ ọba èyí tí ọba ń wọ̀ àti ẹṣin tí ọba má a ń gùn, pẹ̀lú ọ̀kan lára adé ọba kí a fi dé e ní orí Jẹ́ kí a fí aṣọ àti ẹṣin lé ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ lọ́wọ́, kí wọn wọ aṣọ náà fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, kí wọn sì sìn-ín gun ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, kí wọn má a kéde níwájúu rẹ̀ pé, Èyí ni a ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!  Ọba pàṣẹ fún Hámánì pé, Lọ lẹ́ṣẹ̀ kan náà Mú aṣọ náà àti ẹṣin kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ fún Módékáì araa Júù, ẹni tí ó jókòó sí ẹnu ọ̀nà ọba Má ṣe fi ohunkóhun sílẹ̀ nínú ohun tí o ti yàn Bẹ́ẹ̀ ni Hámánì ṣe mú aṣọ àti ẹṣin náà Ó fi wọ Módékáì, Módékáì sì wà lórí ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, ó sì ń kéde níwájúu rẹ̀ pé, Èyí ni a ó ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá! Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Módékáì padà sí ẹnu ọ̀nà ọba Ṣùgbọ́n Hámánì ṣáré lọ ilé, ó sì bo oríi rẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, Ó sì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ síi fún Ṣérésì ìyàwóo rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀ Àwọn olùbádámọ̀ràn an rẹ̀ àti ìyàwó o rẹ̀ sọ fún-un pé, Níwọ̀n ìgbà tí Módékáì ti jẹ́ ẹ̀yà Júù, níwájú ẹni tí ìṣubúu rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀, ìwọ kò lè rí ẹ̀yìn in rẹ̀—dájúdájú ìwọ yóò parun! Bí wọ́n ṣe ń báa sọ̀rọ̀, àwọn ìwẹ̀fà ọba wọlé, wọ́n sì kán Hámánì lójú láti lọ sí ibi àṣè tí Ẹ́sítà ti pèsè Síso Hámánì Rọ̀ Ọba àti Hámánì sì lọ sí àpèjẹ pẹ̀lú Ẹ́sítà ayaba, Bí wọ́n sì ṣe ń mu wáìnì ní ọjọ́ kejì yìí, ọba sì tún béèrè pé, Ẹ́sítà ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ A ó sì fi fún ọ Kí ni ìbéèrè rẹ Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọbaà mi, n ó fi fún ọ Nígbà náà ni ayaba Ẹ́sítà dáhùn, Bí èmi bá rí ojú reree rẹ, ìwọ ọba, bí ó bá sì tẹ́ ọláà ńlá à rẹ lọ́rùn, fún mi ní ẹ̀míì mi-èyí ni ẹ̀bẹ̀ mi Kí o sì pa àwọn ènìyàn mi mọ́-èyí ni ìbéèrè mi Nítorí a ti ta èmi àti àwọn ènìyàn mi fún àwọn tí yóò pa wá run, à ti ṣe ìdájọ́ wa fún pípa àti píparẹ́ Bí a bá ti lẹ̀ tàwá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ǹbá dákẹ́, nítorí irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ kò tó èyí tí à ń yọ ọba lẹ́nu sí Ọba Ṣéríṣésì sì bi Ésítà ayaba léèrè pé, ta a ni ẹni náà Níbo ni ẹni náà wà tí kò bẹ̀rù láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ Ésítà sọ wí pé, alátakò àti ọ̀ta náà ni Hámánì aláìníláárí yìí, Nígbà náà ni Hámánì wárìrì níwájú ọba àti ayaba Ọba sì dìde pẹ̀lú ìbínú, ó fi wáìnì sílẹ̀ ó sì jáde lọ sí àgbàlá ààfin Ṣùgbọ́n nígbà tí Hámánì, ti ríi dájú pé ọba ti pinnu láti pa òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Ẹ́sítà ayaba nítorí ẹ̀míi rẹ̀ Bí ọba ṣe padà dé láti àgbàlá ààfin wá sí gbọ̀ngán àsè náà, Hámánì ṣubú sórí àga tí Ẹ́sítà ayaba fẹ̀yìntì Ọba sì pariwo pé, Yóò ha tún tẹ́ ayaba níbí yìí, nínú ilé, ní ojú mi bí Ní kété tí ọba sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde, wọ́n da aṣọ bo Hámánì lójú Nígbà náà Háríbónà ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà tó ń dúró níwájú ọba, sọ wí pé, igi tí ó ga tó ìwọ̀n mítà mẹ́talélógún ni Hámánì ti rì sí ẹ̀gbẹ́ ilée rẹ̀ Ó ṣeé fún Módékáì, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọba Ọba wí pé, ẹ ṣo ó rọ̀ sórí i rẹ́! Wọ́n sì ṣo Hámánì sórí igi tí ó ti pèṣè sílẹ̀ fún Módékáì, ìbínú ọba sì rọ̀ Àṣẹ Ọba Nítorí Awọn Júù Ní ọjọ́ kan náà ni ọba Ṣérísésì fún Ésítà ayaba ní ilée Hámánì, ọ̀ta àwọn Júù Módékáì sì wá síwájú ọba, nítorí Ẹ́sítà ti sọ bí ó ṣe jẹ́ sí ọba Ọba sì bọ́ òrùka dídán an rẹ̀, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ọ Hámánì ó sì fi fún Módékáì, Ẹ́sítà sì yàn án gẹ́gẹ́ bí olóórí ilée Hámánì Ẹ́sítà sì tún bẹ ọba lórí ìkúnlẹ̀, pẹ̀lú omijé lójú Ó bẹ̀ẹ́ kí ó fi òpin sí ètò búburú Hámánì ará Ágágì, èyí tí ó ti pète fún àwọn Júù Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá aládé wúrà sí Ẹ́sítà ó sì dìde, ó dúró níwájúu rẹ̀ Ó wí pé, Bí ó bá wu ọba, tí ó bá sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ojú rere tí ó sì rò pé ohun tí ó dára ni láti ṣe, tí ó bá sì ní inú dídùn pẹ̀lúu mi, jẹ́ kí a kọ ìwé àṣẹ láti yí ète tí Hámánì ọmọ Hámédátà, ará Ágágì, tí ó kọ́ pàṣẹ pé kí a pa àwọn Júù tí wọ́n wà ní gbogbo àgbáyé ìjọba ọba run Nítorí báwo ni èmi yóò ṣe fara dàá tí èmi yóò sì rí kí ibi máa ṣubú lu àwọn ènìyàn mi Báwo ni èmi yóò ṣe fara dàá, tí èmi yóò sì máa wo ìparun àwọn ìdíléè mi Ọba Ṣéríṣésì dá Ẹ́sítà ayaba àti Módékáì aráa Júù náà lóhùn pé, Nítorí Hámánì kọ lu àwọn aráa Júù, èmi ti fi ilée rẹ̀ fún Ẹ́sítà, wọ́n sì ti ṣo ó kọ́ sórí igi Nísinsin yìí, kọ ìwé àṣẹ mìíràn ní orúkọ ọba bí àwọn Júù ṣe jẹ́ pàtàkì sí ọ, kí o sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì dìí-nítorí kò sí àkọsílẹ̀ tí a bá ti kọ ní orúkọ ọba tí a sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì tí a lè yìí padà Lẹ́ṣẹ̀ kan náà àwọn akọ̀wé ọba péjọ ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, oṣù sífánì Wọ́n kọ gbogbo àṣẹ Módékáì sí àwọn Júù, àti sí àwọn alákòóṣo baálẹ̀ àti àwọn ọlọ́lá ìgbèríko mẹ́tadínláàdóje tí ó lọ láti Ińdíà títí ó fi dé kúsì Kí a kọ àṣẹ náà ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé àti bí èdè olúkúlùkù àti pẹ̀lú sí àwọn Júù ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé àti èdè e wọn Modékáì sì fi àṣẹ ọba Ṣéríṣésì kọ̀wé, ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀, ó rán-an lọ ní kíákíá, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ ayaba, bí àṣà àwọn tí wọ́n ń gun ẹṣin tí ó yára, ní pàtàkì èyí tí a ń bọ́ fún ọba Àṣẹ ọba sì dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní gbogbo ìlú láti kó ara wọn jọ kí wọn sì dáàbò bo ara wọn láti pa, láti run àti láti kọlu ogunkógun orílẹ̀ èdè kórílẹ̀ èdè kankan tàbí ìgbéríko tí ó bá fẹ́ kọ lù wọ́n, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn kí ẹ sì kó gbogbo ohun ìní àwọn ọ̀taa wọn Ọjọ́ tí a yàn fún àwọn Júù ní gbogbo agbégbé ọba Ṣéríṣésì láti ṣe nǹkan yìí ni ọjọ́ kẹtàlá èyí tí í ṣe oṣu kejìlá, oṣù Ádárì Ọkàn ìwé àṣẹ náà ni kí a gbé jáde gẹ́gẹ́ bí òfin ní gbogbo ìgbéríko kí ẹ sì jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn ìlú nítorí àwọn Júù yóò leè múra ní ọjọ́ náà láti gbẹ̀san fún ara wọn lára àwọn ọ̀taa wọn Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ ayaba bí àṣà tí wọ́n ń gun ẹṣin ọba, sáré jáde, wọ́n sáré lọ nípa àṣẹ ọba A sì tún gbé àṣẹ náà jáde ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúṣà Módékáì sì kúrò níwájú ọba, ó wọ aṣọ aláró àti funfun, ó dé adé e wúrà ńlá pẹ̀lú ìgbànú eléṣèé àlùkò dáradára, ìlú Ṣúṣà sì ṣe àjọyọ̀ ńlá Àsìkò ìdùnú àti ayọ̀, inú dídùn àti ọlá ni ó jẹ́ fún àwọn Júù Ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú, ní gbogbo ibi tí àṣẹ ọba dé, ni ayọ̀ àti inú dídùn ti wà láàrin àwọn Júù, wọ́n sì ń ṣe àsè àti àjọyọ̀ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú tó kù sọ ara wọn di Júù nítorí ẹ̀rù àwọn Júù bà wọ́n Àwọn Júù Yọ Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Ádárì, tí ó yẹ kí a mú àṣẹ tí ọba pa wá sí ìmúṣẹ Ní ọjọ́ yìí ni ọ̀tá àwọn Júù rò pé àwọn yóò borí i wọn, ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ti yìí padà, àwọn Júù sì na ọwọ́ agbára tó ga lórí àwọn tí ó kóòríra wọn Àwọn Júù pé jọ ní àwọn ìlú u wọn ní gbogbo agbégbé ọba Ṣéríṣésì láti kọlu àwọn tó ń wá ìparun wọn Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè dojú kọ wọ́n, nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ìlú tó kù ń bẹ̀rù u wọn Gbogbo àwọn ọlọ́lá ìgbéríko, àwọn alákòóso, àwọn baálẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ ọba ran àwọn Júù lọ́wọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù u Módékáì Módékáì sì jẹ́ ẹni pàtàkì ní ààfin, òkìkíi rẹ̀ sì tàn jákè jádò àwọn ìgbéríko, ó sì ní agbára kún agbára Àwọn Júù sì gé gbogbo àwọn ọ̀tá a wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì run wọ́n, wọ́n sì ṣe ohun tí ó wù wọ́n sí àwọn tí ó kóòríra wọn Ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúṣà, àwọn Júù pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọkùnrin run Wọ́n sì tún pa parisánídátà, Dálífónì, Ásípátà, Pórátà, Ádálíyà, Árídátà, Parimásítà, Áríṣáyì, Árídáyì àti Fáíṣátà, Àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hámánì, ọmọ Hámédátà, ọ̀ta àwọn Júù Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ ọ wọn lé ìkógún un wọn Ní ọjọ́ náà gan-an ni a mú iye àwọn tí a pa ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúṣà wá fún ọba Ọba sì sọ fún Ẹ́sítà ayaba pé, Àwọn Júù ti pa ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀ta ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí i ṣe ọmọ Hámánì ní ilé ìṣọ́ Ṣúṣà run Kí ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbèríko ọba tó kù Báyìí kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ A ó fi fún ọ Kí ni ìbéèrè rẹ A ó sì tún fi fún ọ Ẹ́sítà sì dáhùn pé, Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, fún àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní kí wọn ṣe bákan náà ní ọ̀la, kí a sì so àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà rọ̀ sórí igi Nítorí náà ọba pàṣẹ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀ A sì gbé àṣẹ kan jáde ní Ṣúṣà, wọ́n sì so àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hámánì kọ́ Àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà sì péjọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì, wọ́n sì pa ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin ní Ṣúṣà, Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ ọ wọn lé ìkógún un wọn Lákókò yìí, àwọn tó kù nínú àwọn Júù tí wọ́n wà ní agbégbé ọba náà tún kó ara wọn jọ láti dáàbò bo ara wọn kí wọn sì sinmi lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn Wọ́n sì pa ẹgbàá mẹ́tadínlógójì ó lé ẹgbẹ̀rin àwọn tí ó kóòríra wọn ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ọ wọn lé ìkógún un wọn Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Ádárì, wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àṣè àti ayọ̀ Àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ Kẹẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àṣè àti ayọ̀ Nítorí náà ni àwọn Júù-tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àṣè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn Módékáì ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ó sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù jákèjádò àgbáyé ọba Ṣéríṣésì, tí ó wà ní tòòsí àti àwọn tí ó wà ní jìnnà réré, Láti lè máa ṣe àjọyọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù Ádárì ní ọdọọdún Gẹ́gẹ́ bí àkókò tí àwọn Júù gba ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta a wọn, àti bí oṣù tí ìbànújẹ́ ẹ wọn yí padà di ayọ̀ àti tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn di ọjọ́ àjọyọ̀ Ó kọ ọ́ sí wọn láti máa pa ọjọ́ náà mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àṣè àti ọjọ́ ayọ̀ kí wọn sì máa fi oúnjẹ fún ara wọn, kí wọn sì máa fi ẹ̀bùn fún àwọn aláìní Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Júù gbà láti máa ṣe àjọyọ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ń ṣe bí Módékáì ti kọ̀wé sí wọn Nítorí Hámánì ọmọ Hámédátà, aráa Ágágì, ọ̀ta gbogbo àwọn Júù, ti gbérò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di Púrì fún ìṣọdahoro àti ìparun wọn Ṣùgbọ́n nígbà tí Ẹ́sítà sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hámánì ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí oun fúnra rẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi Nítorí ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé yìí àti nítorí ohun tí wọ́n ti rí àti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn, Àwọn Júù fi lélẹ̀, wọ́n sì gbàá gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ara wọn àti fún irú àwọn ọmọ wọn àti gbogbo àwọn tí ó dara pọ̀ mọ́ wọn, kò sì ní kúrò, wọn yóò sì máa pa àwọn ọjọ́ méjèèjì yìí mọ́ ní gbogbo ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ àti àkókò tí a yàn A gbọdọ̀ máa ṣe ìrántí àwọn ọjọ́ wọ̀nyí kía sì máa pa wọ́n mọ́ ní ìrandíran ní gbogbo ìdílé, àti ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú A gbọdọ̀ máa ṣe àwọn ọjọ́ Púrímù wọ̀nyí ní ìgbà gbogbo bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ di ohun ìgbàgbé láàrin irú àwọn ọmọ wọn Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ́sítà ayaba, ọmọbìnrin Ábíháílì, pẹ̀lú Módékáì aráa Júù, kọ̀wé pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìdí ìwé kejì nípa Púrímù yìí múlẹ̀ Módékáì sì kọ ìwé ránsẹ́ sí gbogbo àwọn Júù, sí ìgbéríko mẹ́tadínláàdóje ní ilé ọba Ṣéríṣésì ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ Láti fi ìdí àwọn ọjọ́ọ Púrímù yìí múlẹ̀ ní àkókò tí wọ́n yàn, gẹ́gẹ́ bí Módékáì àti Ẹ́sítà ayaba ti pa á láṣẹ fún wọn, àti bí wọ́n ṣe fi lélẹ̀ fún ara wọn àti irú àwọn ọmọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú àkókò ààwẹ̀ àti ẹkún un wọn Àṣẹ Ẹ́sítà sì fi ìdí ìlànà Púrímù wọ̀nyí múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé àkọsílẹ̀ A ni Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Lára Ìwọ̀nyí ni àwọn orúkọ ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n bá Jákọ́bù lọ sí Éjíbítì, ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ Rúbẹ́nì, Símónì, Léfì àti Júdà, Ísákárì, Ṣébúlúnì àti Bẹ́ńjámínì, Dánì àti Náfítalì, Gádì àti Ásérì Àwọn ìran Jákọ́bù sì jẹ́ àádọ́rin ní àpapọ̀ Jóṣẹ́fù sì ti wà ní Éjíbítì Wáyìí o, Jóṣẹ́fù àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran náà kú, Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì ń bí sí i, wọ́n ń pọ̀ sí i gidigidi, wọ́n kò sì ní òǹkà tí ó fi jẹ́ pé wọ́n kún ilẹ̀ náà Nígbà náà ni ọba túntún ti kò mọ nípa Jósẹ́fù jẹ ní ilẹ̀ Éjíbítì Ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ Ẹ wò ó, àwọn ará Ísírẹ́lì ti pọ̀ ní iye àti agbára jù fún wa Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti dá wọn lẹ́kun, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i Bí ogun bá sì bẹ́ sílẹ̀, wọn yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa, wọn yóò sì da ojú ìjà kọ wá, wọn yóò sì sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ yìí Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára Wọ́n sì kọ́ Pítómi àti Ráméṣéṣì gẹ́gẹ́ bí ìlú ìkó ìṣúra pamọ́ sí fún Fáráò Ṣùgbọ́n bí a ti ń ni wọ́n lára tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, ti wọn sì ń tàn kálẹ̀ Nítorí náà, àwọn ará Éjíbítì bẹ̀rù nítorí àwọn ará Ísírẹ́lì Wọ́n sì mú wọn ṣiṣẹ́ àṣekú láìkáánú wọn Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ ẹ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko àwọn ará Éjíbítì ń lò wọ́n ní ìlòkulò Ọba Éjíbítì sọ fún àwọn agbẹ̀bí Hébérù ti orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣífúrà àti Púà pé Nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Hébérù, tí ẹ sì kíyèsí wọn lórí ìkúnlẹ̀ ìrọbí wọn, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin ni ọmọ náà, ẹ pa á ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, ẹ jẹ́ kí ó wà láàyè Ṣùgbọ́n àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Éjíbítì ti wí fún wọn wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wà láàyè Ọba Éjíbítì pe àwọn agbẹ̀bí ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí , Èéṣe tí ẹ̀yin fi dá àwọn ọmọkùnrin si Àwọn agbẹ̀bí náà sì dá Fáráò lóhùn pé, Àwọn obìnrin Hébérù kò rí bí àwọn obìnrin Éjíbítì, wọ́n ní agbára, wọ́n sì ti máa ń bí ọmọ kí àwọn agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn Nítorí náà Ọlọ́run ṣàánú fún àwọn agbẹ̀bí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń le sí i, wọ́n sì ń pọ̀ sí i jọjọ Nítorí pé àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, Ọlọ́run sì fún wọn ni ìdílé ti wọn Nígbà náà ni Fáráò pàṣẹ yìí fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ pé Gbogbo ọmọkùnrin tí a bí ni kí ẹ gbé jù sínú odò Náílì, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọbìnrin ni kí ẹ jẹ́ kí wọn ó wà láàyè Ìyọnu Eṣú Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Lọ sí ọ̀dọ̀ Fáráò, mo ti ṣé ọkàn Fáráò le àti ọkàn àwọn ìjòyè rẹ̀, kí èmi kí o ba le ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrin wọn Kí ẹ̀yin ki ó le sọ fún àwọn ọmọ yin àti àwọn ọmọ ọmọ yín Bí mo ti jẹ àwọn ará Éjíbítì níyà àti bí mo ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu láàrin wọn Kí ìwọ ba á le mọ̀ pé èmi ni Olúwa Nígbà náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, ti wọn sí wí fún pé, Èyí ni Olúwa , Ọlọ́run àwọn Hébérù sọ Yóò ti pẹ́ to ti ìwọ yóò kọ̀ láti tẹrí ara rẹ ba ní iwájú mi Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn lọ, èmi yóò mú eṣú wa sí orílẹ̀-èdè rẹ ní ọ̀la Wọn yóò bo gbogbo ilẹ̀ Wọn yóò ba ohun gbogbo tí ó kù fún ọ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́, tí ó fi dórí gbogbo igi tí ó ń dàgbà ni ilẹ̀ rẹ Wọn yóò kún gbogbo ilé rẹ àti ilé àwọn ìjòyè rẹ àti ilé gbogbo àwọn ará Éjíbítì Ohun ti baba rẹ tàbí baba baba rẹ kò tí ì rí láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ilẹ̀ náà títí di àkókò yìí   Nígbà náà ni Mósè pẹ̀yìndà kúrò níwájú Fáráò Àwọn ìjòyè Fáráò sọ fún Yóò ti pẹ to tí ọkùnrin yìí yóò máa mú ìyọnu bá wa Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí lọ, kí wọn kí ó le sìn Olúwa Ọlọ́run wọn Ṣe ìwọ kò ṣe àkíyèsí ṣíbẹ̀ pé, ilẹ̀ Éjíbítì ti parun tán Nígbà náà ni a mú Árónì àti Mósè padà wá sí iwájú Fáráò ó sì wí fún wọn pé Ẹ lọ sìn Olúwa Ọlọ́run yín Ṣùgbọ́n àwọn ta ni nínú yín ni yóò ha lọ Mósè dáhùn ó wí pé, A ó lọ pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti àgbà wa, pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ọkùnrin àti ọmọ wa obìnrin pẹ̀lú agbo àgùntàn wa àti agbo màlúù wa nítorí pé a gbọdọ̀ ṣe ajọ fún Olúwa Fáráò sì wí pé, Mo fi Olúwa búra pé èmi kí yóò jẹ́ kí ẹ lọ, pẹ̀lú àwọn obìnrin yín àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, dájúdájú èrò ibi ní ń bẹ nínú yín Rárá! Ọkùnrin yín nìkan ni kí ó lọ, láti lọ sin Olúwa , ní wọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé èyí ni ẹ̀yín ń béèrè fún Wọ́n sì lé Mósè àti Árónì kúrò ní iwájú Fáráò Ní ìgbà náà ni Ọlọ́run sọ fún Mósè, Gbé ọwọ́ rẹ sókè lórí Éjíbítì kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣú bo gbogbo ilẹ̀, kí ó sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko wọn jẹ́, àní gbogbo ohun tí òjò yìnyín kò bájẹ́ tan Nígbà náà ni Mósè na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ sórí ilẹ̀ Éjíbítì, Olúwa sì mú kí afẹ́fẹ́ láti ìlà oòrùn fẹ́ kọjá lórí ilẹ̀ náà ni gbogbo ọ̀sán àti ni gbogbo òru ni ọjọ́ náà Ní òwúrọ̀ afẹ́fẹ́ náà ti gbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ Esú wá Wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n wà ní ibi gbogbo ní orí ilẹ̀ ní àìmoye, ṣáájú àkókò yìí kò sí irú ìyọnu Esú bẹ́ẹ̀, rí kò sì ní sí irú rẹ mọ́ lẹ́yìn èyí Wọ̀n bo gbogbo ilẹ̀ tí ilẹ̀ fi di dúdú Wọ́n ba gbogbo ohun tó kù ní orí ilẹ̀ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́ gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ní inú oko àti gbogbo èso tí ó wà lórí igi Kò sí ewe tí ó kù lórí igi tàbí lorí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Íjibítì Fáráò yára ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì, ó sì sọ fún wọn pé, Èmi ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín àti sí i yín pẹ̀lú Nísinsìnyìí ẹ dárí jín mi lẹ́ẹ̀kan sí i kí ẹ sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín kí ó lè mú ìpọ́njú yìí kúrò ní ọ̀dọ̀ mi Nígbà náà ni Mósè kúrò ní iwájú Fáráò ó sì gbàdúrà sí Olúwa Olúwa sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀ oòrùn wá láti gbá àwọn Esú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Éjíbítì lọ sínú òkun pupa Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ Esú kan kò ṣẹ́ kù sí orí ilẹ̀ Éjíbítì Ṣíbẹ̀ Olúwa ṣe ọkàn Fáráò le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run kí okùnkùn báà le bo gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì àní òkùnkùn biribiri Nígbà náà ni Mósè gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì bo gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì fún ọjọ́ mẹ́ta Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìmọ́lẹ̀ ní ibi tí wọn ń gbé Kò sí ẹni tí ó le è ríran rí ẹlòmíràn tàbí kí ó kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ̀ mẹ́ta Ṣíbẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ̀lì ni ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé Fáráò sì ránṣẹ́ pe Mósè ó sì wí fún un pé, Lọ sìn Olúwa , kódà àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé lè lọ pẹ̀lú yín, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó fi agbo àgùntàn àti agbo màlúù yín sílẹ̀ Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé, Ìwọ gbọdọ̀ fún wa láàyè láti rúbọ àti ọrẹ ẹbọ sísun ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa Àwọn ohun ọ̀sìn wa gbọdọ̀ lọ pẹ̀lú wa, a kì yóò fi pátákò ẹṣẹ̀ ẹran sílẹ̀ A ní láti lò lára wọn fún sínsìn Olúwa Ọlọ́run wa, ìgbà tí a bá sì dé ibẹ̀ ni a ó to mọ̀ ohun ti a ó lò láti fi sìn Olúwa Ṣùgbọ́n Olúwa ṣé ọkàn Fáráò le, kò sì ṣetan láti jẹ́ kí wọn lọ Fáráò sọ fún Mósè pé, Kúrò ní iwájú mi! Rí i dájú pé o kò wá sí iwájú mi mọ́! Ọjọ́ tí ìwọ bá rí ojú mi ni ìwọ yóò kú Mósè sì dáhùn pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wí, Èmi kí yóò wá sí iwájú rẹ mọ́ Ikú Àwọn Àkọ́bí Nísínsìn yìí, Olúwa sọ fún Mósè pé èmi yóò mú ìyọnu kan sí i wá sí orí Fáráò àti ilẹ̀ Éjíbítì Lẹ́yìn náà yóò jẹ́ kí ẹ̀yín kí ó lọ kúrò níhín yìí, nígbà tí ó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ yóò lé yín jáde pátápátá Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé kí tọkùnrin tobìnrin wọn béèrè fún ohun èlò fàdákà àti wúrà lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀ Nígbà náà ni Mósè wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, Ní ọ̀gànjọ́ òru èmi yóò la ilẹ̀ Éjíbítì kọjá Gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin tí ó wà ní ilẹ̀ Éjíbítì ni yóò kú, bẹ̀rẹ̀ lórí àkọ́bí ọkùnrin Fáráò tí ó jòkòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, tí ó fi dé orí àkọ́bí ọmọkùnrin ti ẹrú-bìnrin tí ń lọ ọlọ àti gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú Igbe ẹkún ńlá yóò sọ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì Irú ohun búburú tí kò sẹlẹ̀ rí tí kò sí tún ni sẹlẹ̀ mọ́ Ṣùgbọ́n láàrin àwọn ará Ísírẹ́lì ajá lásán kò ní gbó àwọn ènìyàn tàbí àwọn ẹran wọn Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ti fi ìyàtọ̀ sáàrín àwọn ará Éjíbítì àti Ísírẹ́lì Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ wọ̀nyí yóò tọ̀ mí wá, wọn yóò wólẹ̀ ni iwájú, mi wọn yóò sì máa wí pé, Lọ àti àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀ lé ọ! Lẹ́yìn náà èmi yóò jáde Nígbà náà ni Mósè fi ìbínú jáde kúrò ní iwájú Fáráò Olúwa ti sọ fún Mósè pé, Fáráò yóò kọ̀ láti fetí sílẹ̀ sí ọ kí iṣẹ́ ìyanu mí le pọ̀ sí ní Éjíbítì Mósè àti Árónì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí níwájú Fáráò, ṣùgbọ́n Olúwa sé ọkàn Fáráò le, òun kò sí jẹ́ kí àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni orílẹ̀ èdè rẹ̀ Àjọ Ìrékọjá Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì ni ilẹ̀ Éjíbítì pé, Osù yìí ni yóò jẹ́ osù àkọ́kọ́ fún yín oṣù àkọ́kọ́ nínú ọdún yín Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì pé ni ọjọ́ kẹwàá oṣù yìí, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan yóò mú ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan fún ìdílé rẹ̀, ọ̀kan fún agbo ilé kọ̀ọ̀kan Bí ìdílé kan bá kéré jù fún odidi ọ̀dọ́ àgùntàn kan, kí wọn kí ó ṣe àjọpín ọ̀kan pẹ̀lú aládùúgbò wọn ti ó sun mọ́ wọn kí wọ́n lo iye ènìyàn ti wọn jẹ láti ṣe òdìnwọ̀n irú ọ̀dọ́ àgùntàn ti wọn yóò lò ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n ti ẹni kọ̀ọ̀kan lè jẹ Ẹran tí ìwọ yóò mú gbọdọ̀ jẹ́ akọ ọlọ́dùn kan tí kò lábùkù, ìwọ lè mú lára àgbò tàbí ewúrẹ́ Ṣe ìtọ́jú wọn títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì yóò pa ẹran náà ní àfẹ̀mójúmọ́ Wọn yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò fi kan ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àti òkè ẹnu ọ̀nà àbáwọlé níbi tí wọ́n bá ti jẹ ẹran ọ̀dọ́ àgùntàn náà Ní òru ọjọ́ kan náà, wọn yóò jẹ ẹran tí a ti fi iná sun, pẹ̀lú ewe ewúro àti búrẹ̀dì aláìwú Ẹ má ṣe jẹ ẹran náà ni tútù tàbí ní bíbọ̀ nínú omi, ṣùgbọ́n kí ẹ fi iná sun orí, ẹsẹ̀ àti àwọn nǹkan inú ẹran náà Ẹ má ṣe fi èyíkéyìí sílẹ̀ di òwúrọ̀ ọjọ̀ kejì, bí ó bá sẹ́ kú di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ẹ jó o níná Báyìí ni ẹ̀yìn yóò ṣe jẹ tí ẹ̀yin ti àmùrè ní ẹ̀gbẹ́ yín, sáńdà yín ní ẹsẹ̀ yín àti ọ̀pá yín ni ọwọ́ yín Ẹ yára jẹ ẹ́, oúnjẹ àjọ ìrékọjá Olúwa ni Ní òru ọjọ́ yìí kan náà ni èmi yóò la gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì kọjá, èmi yóò sì pa gbogbo àkọ́bí àtènìyàn, àtẹranko, èmi yóò mú ìdájọ́ wà sí orí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Éjíbítì Èmi ni Olúwa Ẹ̀jẹ̀ ni yóò jẹ́ àmì fún un yín ní àwọn ilé tí ẹ̀yin wà, nígbà tí èmi bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, èmi yóò ré e yín kọjá Ìyọnu kì yóò kàn yín nígbà tí èmi bá kọlu Éjíbítì láti pa wọ́n run Èyí ni ọjọ́ tí ẹ̀yin yóò máa ṣe ìrántí láàrin àwọn ìran tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn ni ẹ̀yin yóò ti máa ṣe àjọ ọdún rẹ fún Olúwa ìlànà tí yóò wà títí ayé Fún ọjọ́ méje ni ẹ̀yin yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ ó gbé ìwúkàrà kúrò ni ilé yín, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú láti ọjọ́ kìn-ín-ní di ọjọ́ keje ni kí a yọ kúrò ni Ísírẹ́lì Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí ẹ pe àpèjọ mímọ́, kí ẹ sì pe àpèjọ mímọ́ mìíràn ni ọjọ́ keje Ẹ má ṣe se iṣẹ́ kankan ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, yàtọ̀ fún pípèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn láti jẹ Èyí ni gbogbo ohun tí ẹ̀yin lè ṣe Ẹ ṣe àpèjẹ àkàrà aláìwú, nítorí ọjọ́ yìí ni mo mú un yín jáde ni Éjíbítì Ẹ ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí yóò wà títí ayé ní àwọn ìran tí ń bọ̀ Búrẹ́dì ti kò ni ìwúkàrà ni ẹ̀yin yóò jẹ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀kànlélógún osù àkọ́kọ́ Fún ọjọ́ méje ni ẹ kò gbọ́dọ́ ni ìwúkàrà nínú ilé yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó ni ìwúkàrà nínú ni a ó yọ kúrò ni àárin àwùjọ Ísírẹ́lì, ìbá à ṣe àlejò tàbí ẹni tí a bí ní ilẹ̀ náà Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe Ní ibikíbi tí ẹ̀yin bá ń gbé, kí ẹ̀yin kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà Ní ìgbà náà ni Mósè pé gbogbo àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, ó sì sọ fún wọn pé, Ẹ jáde lọ, kí ẹ sì yan ọ̀dọ́ àgùntàn fún àwọn ìdílé yín, kí ẹ sí pa ẹran àjọ ìrékọjá Olúwa Ẹ̀yin yóò sì mú ìdí-ewé hísópù, ẹ tì í bọ inú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà nínú ọpọ́n kí ẹ sì fi kun òkè à bá wọ ẹnu ọ̀nà ilé yín àti ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìlẹ̀kùn yín Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ jáde sí òde títí di òwúrọ̀ Ní ìgbà tí Olúwa bá ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Éjíbítì láti kọlù wọn, yóò rí ẹ̀jẹ̀ ni òkè ẹnu ọ̀nà àti ni ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé yín, yóò sì re ẹnu ọ̀nà ilé náà kọjá, kì yóò gba apanirun láàyè láti wọ inú ilé e yín láti kọlù yín Ẹ pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ ó máa ṣe títí ayérayé láàrin yín àti àwọn ìran yín Nígbà tí ẹ̀yin bá de ilẹ̀ tí Olúwa yóò fi fún un yín bí òun ti ṣe ìlérí, ẹ máa kíyèsí àjọ yìí Ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín, Kí ni ohun tí àjọ yìí túmọ̀ sí fún un yín Ẹ sọ fún wọn ni ìgbà náà, Ẹbọ ìrékọjá sí Olúwa ni, ẹni tí ó rékọjá ilé e wa ni ìgbà tí ó kọlu àwọn ara Éjíbítì Tí ó si da wa sí nígbà ti ó pa àwọn ara Éjíbítì   Àwọn ènìyàn sì tẹríba láti sìn Àwọn Ísírẹ́lì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè àti Árónì Ní ọ̀gànjọ́ òru Olúwa kọlu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Éjíbítì, láti orí àkọ́bí Fáráò tí ó wà ní orí ìtẹ́ títí dé orí àkọ́bí ẹlẹ́wọ̀n tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n àti àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn ara Éjíbítì dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, igbe ẹkún ńlá sì gba gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, nítorí kò sí ilé kan tí ó yọ sílẹ̀ tí ènìyàn kan kò ti kú Fáráò sì ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì ní òru, ó sì wí pé, Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì! Ẹ lọ láti sin Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹ ti béèrè Ẹ kó agbo àgùntàn yín àti agbo màlúù yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti sọ, kí ẹ sì máa lọ, kí ẹ sì súre fún mi Àwọn ara Éjíbítì ń rọ àwọn ènìyàn náà láti yára máa lọ kúrò ní ilẹ̀ wọn Wọ́n wí pé, Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ gbogbo wa ni yóò kú! Àwọn ènìyàn náà sì mú ìyẹ̀fun pípò kí wọn tó fi ìwúkàrà sí i, wọ́n gbe le èjìká wọn nínú ọpọ́n tí wọ́n ti fi aṣọ dì Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè ti sọ fún wọn Wọ́n sì béèrè fún ohun èlò fàdákà àti wúrà àti fún aṣọ pẹ̀lú Olúwa ti mú kí àwọn ènìyàn yìí rí ojú rere àwọn ará Éjíbítì wọ́n sì fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún, wọ́n sì ko ẹrù àwọn ará Éjíbítì Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rìn láti Rámẹ́sẹ́sì lọ sí Sukoti Àwọn ọkùnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rìn tó ọ̀gbọ̀n ọ̀kẹ́ ni iye láì ka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn ni ó bá wọ́n lọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn, agbo àgùntàn àti agbo màlúù Pẹ̀lú ìyẹ̀fun tí kò ní ìwúkàrà nínú tí wọ́n gbé jáde láti Éjíbítì wá ní wọ́n fi ṣe àkàrà aláìwú Ìyẹ̀fun náà kò ni ìwúkàrà nínú nítorí a lé wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wọn kò si rí ààyè láti tọ́jú oúnjẹ fún ara wọn Iye ọdun ti àwọn ará Ísírẹ́lì gbé ní ilẹ̀ Éjíbítì jẹ́ irínwó ọdún ó lé ọgbọ̀n Ní ọjọ́ ti irínwó ọdún ó le ọgbọ̀n pé gan an ni gbogbo ènìyàn jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì Nítorí pé, Olúwa ṣe àìsùn ni òru ọjọ́ náà láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ní òru yìí ni gbogbo Ísírẹ́lì ní láti máa se àìsùn láti fi bu ọlá fún Olúwa títí di àwọn ìran tí ń bọ̀ Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé, Ìwọ̀n yìí ni àwọn òfin fún àjọ ìrékọjá Àjòjì kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ Ẹrú tí ẹ̀yin bá rà lè jẹ́ nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀yin bá ti kọ ọ́ ní ilà, Ṣùgbọ́n àlejò àti alágbàṣe kò ni jẹ nínú rẹ̀ Nínú ilé ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ẹ kò gbọdọ̀ mú èyíkéyìí nínú ẹran náà jáde kúrò nínú ilé Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan nínú egungun rẹ̀ Gbogbo àjọ Ísírẹ́lì ni ó gbọdọ̀ ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀ Àjòjì ti ó bá ń gbé ní àárin yín ti ó bá fẹ́ kópa nínú àjọ ìrékọjá Olúwa , ni o gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọmọkùnrin ilé rẹ̀ ní ìlà ní ìgbà náà ni ó lè kó ipa gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí a bí ní ilẹ̀ náà Gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí a kò bá kọ ní ìlà, wọ́n kò ni jẹ ni ara rẹ̀ Òfin yìí kan náà ni ó mú àwọn ọmọ tí a bí ni ilẹ̀ náà àti àwọn àlejò tí ń gbé ní àárin yín Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè àti Árónì Àti pé ní ọjọ́ náà gan-an ni Olúwa mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì gẹ́gẹ́ bí ìpín ìpín wọn Ìyàsímímọ́ Àwọn Àkọ́bí Olúwa sọ fún Mósè pé, Ẹ ya àwọn àkọ́bí yín ọkùnrin ṣọ́tọ̀ fún mi Èyí ti ó bá jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ tèmi, ìbáà ṣe ènìyàn tàbí ẹranko Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ́ Éjíbítì, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí Olúwa mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára Ẹ má se jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú Òní, ní oṣù Ábíbù lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Éjíbítì Ní ìgbà tí Ọlọ́run mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ ẹ Kénánì, Hítì, Ámórì, Hífì àti ilẹ̀ àwọn Jébúsì ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún Olúwa Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí Olúwa ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì Ṣiṣe èyí yóò wà fún àmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí ìránlétí ni iwájú orí rẹ tí yóò máa ran ọ létí òfin Olúwa ní ẹnu rẹ Nítorí Olúwa mú ọ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀ Ìwọ gbọdọ̀ pa òfin náà mọ́ ní àkókò tí a yàn bí ọdún tí ń gorí ọdún Lẹ́yìn tí Olúwa tí mú ọ wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kénánì tí ó sì fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí pẹ̀lú ìbúra fún ọ àti fún àwọn baba ńlá rẹ̀, Ìwọ yóò fi àkọ́bí inú rẹ fún Olúwa Gbogbo àkọ́bí ti ó jẹ́ akọ ti ẹran ọ̀sìn rẹ ní ó jẹ́ ti Olúwa Ìwọ yóò fi ọ̀dọ́ àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, ǹjẹ́ kí ìwọ ṣẹ́ ẹ ní ọrùn, gbogbo àkọ́bí ọkùnrin ni kí ìwọ kí ó rà padà, Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín Kí ni èyí túmọ̀ sí Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní Olúwa fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì, kúrò ní oko ẹrú Ní ìgbà ti Fáráò ṣe oríkunkun, ti ó kọ̀ láti jẹ́ kí a lọ, Olúwa pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Éjíbítì, àti ènìyàn àti ẹranko Ìdí èyí ni àwa fi ń fi gbogbo àkọ́bí tí í ṣe akọ rúbọ sí Olúwa láti fi ṣe ìràpadà fún àwọn àkọ́bí wa ọkùnrin Èyí yóò sì jẹ́ àmì ni ọwọ́ yín àti àmì ní iwájú orí yín pé Olúwa mú wa jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá Ní ìgbà tí Fáráò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ, Ọlọ́run kò mú wọn tọ ojú ọ̀nà ti ó la orílẹ̀ èdè àwọn Fílístínì kọjá, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà náà kúrú Nítorí Ọlọ́run sọ pé, Bí wọ́n bá dojú kọ ogun, wọ́n lè yí ọkàn wọn padà kí wọ́n padà sí ilẹ̀ Éjíbítì Nítorí náà Ọlọ́run darí àwọn ènìyàn rọkọ gba ọ̀nà ihà ní apá okùn pupa Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú ìmúra fún ogun Mósè kó egungun Jósẹ́fù pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Jósẹ́fù tí mú kí àwọn ọmọ Isírẹ́lì búra Ó ti wí pé, Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìnín yìí Wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti Súkótì lọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Ẹ́tamù ní etí ihà Olúwa sì ń lọ níwájú wọn, nínú òpó ìkùùkuu ní ọ̀san láti máa ṣe amọ̀nà wọn àti ní òru nínú òpó iná láti máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa lọ nínú ìrìnàjò wọn ní tọ̀sán tòru Ìkùùku náà kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni, òpó iná kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ni òru, ní iwájú àwọn ènìyàn náà Olúwa sọ fún Mósè pé Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọn padà sẹ́yìn, kí wọ́n sì pàgọ́ sí tòsí Pi-Háhírótù láàrin Mígídólù òun òkun, kí wọn kí ó pàgọ́ sí ẹ̀bá òkun, ní òdìkejì Baali-Séfóní Fáráò yóò ronu pé àwọn ọmọ Isírẹ́lì ń ráre káàkiri ní ìdààmú ni àti wí pé ihà náà ti sé wọn mọ́ Èmi yóò sé ọkàn Fáráò le ti yóò fi lépa wọn Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpaṣẹ̀ Fáráò àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Éjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Àwọn Isírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀ Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba Éjíbítì pé àwọn ènìyàn náà ti sá lọ, ọkàn Fáráò àti àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ yí padà sí àwọn ènìyàn, wọ́n sì wí pé, Kí ni ohun tí àwa ṣe yìí Àwa ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ó lọ, a sì ti pàdánù ìsìnrú wọn Ó sì di kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó mú ẹgbẹ̀ta ọmọ ogun oníkẹ̀kẹ́ tí ó jáfáfá jùlọ àti gbogbo ọmọ ogun oníkẹ̀kẹ́ mìíràn ní Éjíbítì, olórí sì wà fún olúkúlùkù wọn Olúwa ṣe ọkàn Fáráò ọba Éjíbítì le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń jáde lọ ní àìbẹ̀rù Àwọn ará Éjíbítì ń lépa wọn pẹ̀lú gbogbo ẹsin kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀, wọ́n sì lé wọn bá ni ibi tí wọ́n pa àgọ́ sí lẹ́bá òkun ní ìhà Pi-Hahírótù, ni òdì kejì Baali-Ṣéfónì Bí Fáráò ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Éjíbítì tó súnmọ́ wọn Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Ísírẹ́lì, wọ́n kígbe sókè sí Olúwa Wọ́n sọ fún Móse pé, Ṣe nítorí pé kò sí ibojì ni Éjíbítì ní ìwọ se mú wa wá láti kú sínú ihà Kí ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa ti ìwọ fi mú wa jáde láti Éjíbítì wá Ǹjẹ́ èyí kọ́ ni àwa sọ fún ọ ni Éjíbítì, Fi wá sílẹ̀, jẹ́ kí àwa máa sin ará Éjíbítì Nítorí kò bá sàn fún wa kí a sin àwọn ará Éjíbítì ju kí a kú sínú ihà yìí lọ! Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, Ẹ ma bẹ̀rù, ẹ dúró sinsin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí Olúwa yóò fifún un yín lónìí Àwọn ará Éjíbítì ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́ Olúwa yóò jà fún un yin kí ẹ̀yin kí ó sáà mu sùúrù Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Èéṣe tí ìwọ fi ń ké pè mí Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì kí wọn máa tẹ̀ṣíwájú Ṣùgbọ́n, gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè, kí o sì na ọwọ́ rẹ sí orí omi òkun, kí ó lè pín níyà kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè la òkun kọjá ni orí ìyàngbẹ ilẹ̀ Nígbà náà ni èmi yóò ṣé ọkàn àwọn ará Éjíbítì le, wọn yóò sì máa lépa wọn Èmi yóò gba ògo fún ara mi lórí Fáráò lórí gbogbo ogun rẹ̀, lórí kẹ̀kẹ́-ògun àti lórí àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ Àwọn ará Éjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa nígbà ti èmi bá gba ògo fún ara mi lórí Fáráò lórí kẹ̀kẹ́-ogun rẹ̀ àti lórí àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ Nígbà náà ni ańgẹ́lì Ọlọ́run tó ti ń ṣááju ogun Ísírẹ́lì lọ, padà o sì rìn ni ẹ̀yìn wọn Òpó ìkùùkuu tí ń rìn ni iwájú wọn sì padà sí í rìn ni ẹ̀yìn wọn Ó sì wà láàrin àwọn ọmọ ogun Éjíbítì àti Ísírẹ́lì Ìkùùkuu sì su òkùnkùn sí àwọn ará Éjíbítì ni òru náà Ṣùgbọ́n ó tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn Ísírẹ́lì ni òru náà Ọ̀kan kò sì súnmọ́ èkejì ni gbogbo òru náà Nígbà náà ni Mósè na ọwọ́ rẹ̀ sí orí òkun, ni gbogbo òru náà ni Olúwa fi lé òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀ Omi òkun sì pínyà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì si la ìyàngbẹ ilẹ̀ kọjá nínú òkun pẹ̀lú ògiri omi ní ọ̀tún àti òsì Àwọn ará Éjíbítì sì ń lépa wọn, gbogbo ẹsin Fáráò, kẹ́kẹ́-ogun àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ wọ́ tọ̀ wọ́n lọ sínú òkun Ní ìsọ́ òwúrọ̀ Olúwa bojúwo ogun àwọn ará Éjíbítì láàrin òpó iná àti ìkùùkuu, ó sì kó ìpayà bá àwọn ọmọ ogun Éjíbítì Ó sì yọ àgbá ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn kí ó bá à le ṣòro fún wọn láti fi kẹ̀kẹ́-ogun náà rìn Àwọn ará Éjíbítì wí pé, Ẹ jẹ́ kí a sá àṣálà kúrò ní iwájú àwọn ará Ísírẹ́lì nítorí Olúwa ń bá wa jà nítorí wọn Olúwa sì wí fún Mósè pé, Na ọwọ́ rẹ sí orí òkun kí omi òkun lè ya padà sórí àwọn ará Éjíbítì, kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti sórí ẹlẹ́sin wọn Mósè sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí òkun, òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ìlẹ̀ mọ́ Àwọn ará Éjíbítì ń sá fún omi òkun, Olúwa sì gbá wọn sínú òkun Omi òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹlẹ́sin àní, gbogbo ọmọ ogun Fáráò ti wọn wọ inú òkun tọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn ti o yè Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì la òkun kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ pẹ̀lú ògiri omi ni ọ̀tún àti òsì wọn Ni ọjọ́ yìí ni Olúwa gba Ísírẹ́lì là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì Ísírẹ́lì sì rí òkú àwọn ará Éjíbítì ni etí òkun Nígbà ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí iṣẹ́ ìyanu ńlá ti Olúwa se fún wọn lára àwọn ará Éjíbítì, àwọn ènìyàn bẹ̀rù Olúwa , wọ́n sì gba Olúwa àti Mósè ìráńṣẹ́ rẹ gbọ́ Orin Mósè àti Míríámù Nígbà náà ni Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ orin yìí sí Olúwa Èmi yóò kọrin sí Olúwa , nítorí òun pọ̀ ní ògo Ẹsin àti ẹni tí ó gùn un ni ó ti sọ sínú òkun Olúwa ni agbára àti orin mi òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga Ologun ni Olúwa , Olúwa ni orúkọ rẹ, Kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti ogun rẹ̀ ni ó mú wọ inú òkun Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáfáfá jùlọ ni ó rì sínú òkun pupa Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀ Wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa , pọ̀ ní agbára Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa , fọ́ àwọn ọ̀ta túútúú Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ Tí ó run wọ́n bí ìgémọ́lẹ̀ ìdí koríko Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ń wọ́jọ pọ̀ Ìsàn omi dìde dúró bí odi Ibú omi sì dìpọ̀ láàrin òkun Ọ̀ta ń gbéraga, ó ń wí pé Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn Èmi ó pín ìkógun Èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn Èmi yóò fa idà mi yọ, ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run Ìwọ fẹ́ èèmí rẹ òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀ wọ́n rì bí òjé ni àárin omi ńlá Ta ni nínú àwọn òrìṣà tó dàbí rẹ, Olúwa Ta ló dàbí rẹ ní títóbi, ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn Tí ń se ohun ìyanu Ìwọ na apá ọ̀tún rẹ Ilẹ̀ si gbé wọn mì Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í ṣákìí ìwọ se amọ̀nà Àwọn ènìyàn náà tí ìwọ ti ràpadà Nínú agbára rẹ ìwọ yóò tọ́ wọn lọ sí ibi ìjókòó rẹ mímọ́ Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrì Ìkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn palẹ́sítínì Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Édómù, Àwọn olórí Móábù yóò wárìrì Àwọn ènìyàn Kénánì yóò sì yọ̀ danu Ìbẹ̀rù-bojo yóò subú lù wọ́n nítorí nína títóbi apá rẹ̀ wọn yóò dúró jẹ́ ẹ́ láì mira bí i òkúta Títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi ré kọjá, Olúwa , Títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi ré kọjá Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́n ni ori òkè ti ìwọ jogún Ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbékalẹ̀, Olúwa Olúwa yóò jọba láé àti láéláé Nígbà ti ẹsin Fáráò, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ wọ inú òkun, Olúwa mú kí omi òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la òkun kọjá Míríámù wòlíì obìnrin, arábìnrin Árónì, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, àwọn obìnrin ti ó tẹ̀lé pẹ̀lú mú ohun èlò orin wọ́n sì ń jó Míríámà kọrin sí wọn báyìí pé Ẹ kọrin sí Olúwa Nítorí òun ni ológo jùlọ Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún Ni òun bi subú sínú òkun Nígbà náà ni Mósè ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde láti òkun pupa lọ sínú aṣálẹ̀ Ṣúrì Wọ́n lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù náà, wọn kò sì rí omi Nígbà tí wọ́n dé Márà, wọn kò lè mu omi Márà nítorí omi náà korò Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mósè wí pé, Kí ni àwa yóò mu Mósè sì ké pe Olúwa , Olúwa sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn Níbẹ̀ ni Olúwa ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò Ó wí pé, Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí òfin Olúwa Ọlọ́run, ti ìwọ si ṣe ohun tí ó tọ́ ni ojú rẹ̀, ti ìwọ sì tẹ̀lé ohun tí ó pàṣẹ, ti ìwọ si pa ìlànà rẹ̀ mọ́ Èmi kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn àrùn wọ̀n-ọn-nì ti mo mú wá sórí àwọn ará Éjíbítì wá sí ara rẹ, nítorí èmi ni Olúwa ti ó mú ọ lára da Nígbà ti wọ́n dé Élímù, nibi ti kànga omi méjìlá àti àádọ́rin ọ̀pẹ gbé wà, wọ́n pàgọ́ ṣíbẹ̀ ni etí omi Oúnjẹ Láti Ọ̀run Ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọ̀nà wọn pọ̀n kúrò ni Élímù, wọ́n dé sí ijù Sínì tí ó wà láàrin Élímù àti Ṣínáì, ni ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kejì tí wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì Ní ijù náà ni ìjọ àwọn ènìyàn ti kùn sí Mósè àti Árónì Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí fún wọn pé, Àwa ìbá ti ọwọ́ Olúwa kú ni Éjíbítì! Níbi tí àwa ti jókòó ti ìkòkò ẹran ti a sì ń jẹ ohun gbogbo tí a fẹ́ ni àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin mú wa wá sí inú ijù yìí láti fi ebi pa wá tí a ó fi kú Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Èmi yóò rọ òjò oúnjẹ láti ọ̀run wá fún yín Àwọn ènìyàn yóò sì máa jáde lọ ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti kó ìwọ̀nba oúnjẹ ti ó tó fún oúnjẹ òòjọ́ wọn Ní ọ̀nà yìí ni, èmi yóò fi dán wọn wò láti mọ bóyá wọn yóò máa tẹ̀lé ìlànà mi Ní ọjọ́ kẹfà, ki wọn kó ìlọ́po méjì èyí ti wọn ń ko ni ojoojúmọ́ tẹ́lẹ̀ Mósè àti Árónì sọ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ni ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo Olúwa , nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa Mósè tún wí pé, Ẹ̀yin yóò mọ pé Olúwa ni, nígbà ti ó bá fún un yín ni ẹran ni ìrọ̀lẹ̀ àti gbogbo oúnjẹ ti ẹ̀yin ń fẹ́ ni òwúrọ̀, nítorí kíkún ti ẹ̀yin ń kùn sí i Ta ni àwa Ẹ̀yin kò kùn sí àwa, Olúwa ni ẹ̀yin kùn sí i Nígbà náà ni Mósè sọ fún Árónì pe, Sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pe, Ẹ wá sí iwájú Olúwa , nítorí òun ti gbọ́ kíkùn yín   Ó sì ṣe bí Árónì ti ń bá gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, wọn si bojúwo ìhà ijù, sì kíyèsi ògo Olúwa si farahàn ni àwọ̀-sánmọ̀ Olúwa sọ fún Mósè pé, Èmi ti gbọ́ kíkun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Sọ fun wọn, Ní àṣálẹ́, ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, àti ni òwúrọ̀ ni ẹ̀yin yóò jẹ oúnjẹ Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín   Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn àparò fò dé, wọ́n sì bo àgọ́ mọ́lẹ̀, ní òwúrọ̀ ìrì sì sẹ̀ yí gbogbo àgọ́ náà ká Nígbà tí ìrì tí ó sẹ̀ bo ilẹ̀ ti lọ, kíyèsí i, ohun tí ó dì, tí ó sì ń yooru bí i yìnyín wà lórí ilẹ̀ Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i, wọ́n bi ara wọn léèrè pé, Kí ni èyí Nítorí pé wọn kò mọ ohun tí i se Mósè sì wí fún wọn pé, Èyí ni oúnjẹ tí Olúwa fi fún un yín láti jẹ Èyí ni ohun tí Olúwa ti pàṣẹ Kí olúklùkù máa kó èyí ti ó tó fún un láti jẹ Ẹ mú òṣùnwọ̀n ómérì kan fún ẹnikọ̀ọ̀kan ti ó wà nínú àgọ́ yín   Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bí a ti sọ fún wọn àwọn kan kó púpọ̀, àwọn kan kó kékeré Nígbà ti wọn fi òṣùwọ̀n ómérì wọ̀n-ọ́n-nì, ẹni ti ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù Ẹnìkọ̀ọ̀kan kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un Mósè sì wí fún wọ́n pé, Kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe kó pamọ́ lára rẹ̀ di òwurọ̀ ọjọ́ kejì Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mósè Wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn Nítorí náà Mósè bínú sí wọn Ní òwúrọ̀, ni ojoojúmọ́ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan ń lọ kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un láti jẹ, bí òòrùn bá sì mú, a sì yọ́ Ní ọjọ́ kẹfà, wọ́n kó ìlọ́po méjì èyí ti wọn ń kó tẹ́lẹ̀ òṣùnwọn ómérì méjì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan àwọn olórí ìjọ ènìyàn sì wá, wọ́n sì sọ èyí fún Mósè Ó sì wí fún wọn pé, Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ Ọ̀la jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ìsinmi mímọ́ fún Olúwa Ẹ yan èyí ti ẹ̀yin ní yan, kí ẹ sì bọ èyí ti ẹ̀yin ní bọ̀ Ẹ tọ́jú èyí ti ó kù sílẹ̀, kí ẹ pa á mọ́ di òwúrọ̀   Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mósè ti pàṣẹ kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin Mósè sì wí fún wọn pé, Ẹ jẹ ẹ́ ní òní nítorí òní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ẹ̀yin kò ni rí i ni orí ilẹ̀ ní ọjọ́ òní Ní ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi kó o, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ keje ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí i fún un yín ni ọjọ́ náà Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó Olúwa sì sọ fún Mósè pé, Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́ Wò ó Olúwa ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni ounjẹ ọjọ́ méjì kí ẹnìkọọkan dúró ni ibi tí ó gbé wà kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sì pe oúnjẹ náà ní Mánà Ó funfun bí irúgbìn kóríáńdà, ó sì dùn bí burẹ́dì fẹlẹfẹlẹ ti a fi oyin ṣe Mósè wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ Ẹ mú òṣùnwọ̀n ómérì mánà kí ẹ sì pa á mọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀, kí wọn kí ó lè rí oúnjẹ ti èmi fi fún un yín jẹ ní ijù, nígbà tí mo mú un yín jáde ni ilẹ̀ Éjíbítì   Nígbà náà ni Mósè sọ fún Árónì pe, Mú ìkòkò kan, kí o sì kó mánà tí ó kún òṣùnwọ̀n ómérì kan sí inú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ ni iwájú Olúwa láti tọ́jú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀ Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè, Árónì gbé mánà sí iwájú ẹ̀rí láti pa á mọ́ Àwọn ará Ísírẹ́lì jẹ mánà fún ogójì ọdún títí wọ́n fi dé ilẹ̀ Kénánì ni ibi ti èso ti wà fún wọn láti jẹ Wọ́n jẹ mánà títí tí wọ́n fi dé ilẹ̀ agbégbé Kénánì Omi Láti Inú Àpáta Gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì si gbéra láti jáde kúrò láti ihà Sínì wọ́n ń lọ láti ibi kan de ibi kan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ Wọ́n pàgọ́ sí Réfídímù Ṣugbọ́n kò sí omi fún àwọn ènìyàn láti mú Àwọn ènìyàn sì sọ̀ fún Mósè, wọ́n wí pé, Fún wa ni omi mu Mósè dá wọn lóhùn wí pé, Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bá mi jà Èése ti ẹ̀yin fi ń dán Olúwa wò Ṣùgbọ́n òùngbẹ ń gbẹ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń kùn sí Mósè, wọ́n wí pé, Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde kúrò ní Éjíbítì láti mú kí òùngbẹ pa àwa, àwọn ọmọ wa àti ohun ọ̀sìn wa ku fún òùngbẹ Nígbà náà ni Mósè gbé ohùn rẹ̀ sókè sí Olúwa pé Kí ni kí èmi kí ó ṣe fún àwọn ènìyàn yìí Wọ́n múra tan láti sọ mi ni òkúta Olúwa sì dá Mósè lóhùn pé, Má a lọ ṣíwájú àwọn ènìyàn, mú nínú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ, mú ọ̀pá tí ìwọ fi lu odò Náìlì lọ́wọ́ kí ó sì máa lọ Èmi yóò dúró ni ibẹ̀ dè ọ ni orí àpáta ni Hórébù Ìwọ ó sì lu àpáta, omi yóò sì jáde nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti mu Mósè sì se bẹ́ẹ̀ ni iwájú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì Ó sì sọ orúkọ ibẹ̀ ni Másá àti Méríba nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀, wọ́n sì dán Olúwa wò, wọ́n wí pé, Ǹjẹ́ Olúwa ń bẹ láàrin wa tàbí kò sí Àwọn ara Ámélékì jáde, wọ́n sì dìde ogun sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Réfídímù Mósè sì sọ fún Jọ́súà pé, Yàn lára àwọn ọkùnrin fún wa, kí wọn ó sì jáde lọ bá àwọn ará Ámélékì jà Ní ọ̀la, èmi yóò dúró ni orí òkè pẹ̀lú ọ̀pá Ọlọ́run ní ọwọ́ mi Jósúà se bí Mósè ti wí fún un, ó sì bá àwọn ará Ámélékì jagun nígbà tí Mósè, Árónì àti Húrì lọ sí orí òkè náà Níwọ̀n ìgbà tí Mósè bá gbé apá rẹ̀ sókè, Ísírẹ́lì n borí ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá sì rẹ apá rẹ̀ sílẹ̀, Ámélékì a sì borí Ṣùgbọ́n apá ń ro Mósè Wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà Árónì àti Húrì sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti òòrùn wọ Jósúà sì fi ojú idà sẹ́gun àwọn ará Ámélékì Olúwa sì sọ fun Mósè pé Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Jóṣúà pẹ̀lú nítorí èmi yóò pa ìràntí Ámélékì run pátapáta kúrò lábẹ́ ọ̀run Mósè sì tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì sọ orúkọ pẹpẹ náà ní Olúwa ni àṣíá mi Ó wí pé, A gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ Olúwa Olúwa yóò bá Ámélékì jagun láti ìran dé ìran Jẹ́tírò Bẹ Mósè Wò Jẹ́tírò, àlùfáà Mídíánì, àna Mósè, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún Mósè àti fún Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀, àti bí Olúwa ti mú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde láti Éjíbítì wá Nígbà náà ni Jẹ́tírò mu aya Mósè tí í se Ṣípórà padà lọ sọ́dọ̀ rẹ Òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì Orúkọ Àkọ́bí ń jẹ́ Gésómù nítorí Mósè wí pé, Èmi ń se àlejò ni ilẹ̀ àjòjì Èkejì ń jẹ́ Élíásérì ó wí pé, Ọlọ́run baba mi ni alátìlẹ́yìn mi, ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ idà Fáráò Jẹ́tírò, àna Mósè, òun àti aya àti àwọn ọmọ Mósè tọ̀ ọ́ wá nínú ihà tí ó tẹ̀dó sí, nítòsí òkè Ọlọ́run Jẹ́tírò sì ti ránṣẹ́ sí Mósè pé, Èmi Jẹ́tírò, àna rẹ, ni mo ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, èmi àti aya àti àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì Mósè sì jáde lọ pàdé rẹ̀, ó tẹríba fún un, ó sì fi ẹnu kò ó ni ẹnu Wọ́n kí ara wọn, wọ́n yọ̀ mọ́ ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ Mósè sọ fún àna rẹ̀ nípa ohun gbogbo ti Olúwa tí se sí Fáráò àti àwọn ará Éjíbítì nítorí Ísírẹ́lì Ó sọ nípa gbogbo ìṣòro tí wọn bá pàdé ní ọ̀nà wọn àti bí Olúwa ti gbà wọ́n là Inú Jẹ́tírò dùn láti gbọ́ gbogbo ohun rere ti Olúwa ṣe fún Ísírẹ́lì, ẹni tí ó mú wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì Jẹ́tírò sì wí pé, Ìyìn ni fún Olúwa , ẹni tí ó gba yín là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì àti lọ́wọ́ Fáráò, ẹni tí ó sì gbà àwọn ènìyàn là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì Mo mọ nísinsìnyìí pé Olúwa tóbi ju gbogbo àwọn òrìṣà lọ nítorí ti ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ìkà àwọn ará Éjíbítì Jẹ́tírò, àna Mósè, mú ọrẹ sísun àti ẹbọ wá fún Ọlọ́run Árónì àti gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì sì wá láti bá àna Mósè jẹun ní iwájú Ọlọ́run Ní ọjọ́ kejì, Mósè jókòó láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ àwọn ènìyàn sì dúró ti Mósè fún ìdájọ́ wọn láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ Nígbà tí àna Mósè rí bí àkókò ti èyí ń gba ti pọ̀ tó àti ti àwọn ènìyàn ti ń dúró pẹ́ tó, ó wí pé, Kí ni èyí tí ìwọ ń se sí àwọn ènìyàn Èéṣe ti ìwọ nìkan jòkóò gẹ́gẹ́ bí adájọ́, nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró yí ọ ká láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́ Mósè dá a lóhùn pé, Nítorí àwọn ènìyàn ń tọ̀ mí wá láti mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run Nígbà tí wọ́n bá ní ẹjọ́, wọn a mú un tọ̀ mí wá, èmi a sì ṣe ìdájọ́ láàrin ẹnìkín-ín-ní àti ẹnikejì, èmi a sì máa mú wọn mọ ofin àti ìlànà Ọlọ́run Àna Mósè dá a lóhùn pé, Ohun ti o ń ṣe yìí kò dára Ìwọ àti àwọn ènìyàn ti ń tọ̀ ọ́ wá yìí yóò dá ara yín ní agara iṣẹ́ yìí pọ̀ jù fún ọ, ìwọ nìkan kò lè dá a ṣe Nísinsìnyìí, fetísílẹ̀ sí mi, èmi yóò sì gbà ọ́ ni ìmọ̀ràn, Ọlọ́run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ Ìwọ gbọdọ̀ jẹ́ aṣojú àwọn ènìyàn wọ̀nyí níwájú Ọlọ́run, ìwọ yóò sì mú èdè àìyedè wá sí iwájú rẹ̀ Kọ́ wọn ní ofin àti ìlànà Ọlọ́run, fi ọ̀nà igbe ayé ìwà bí Ọlọ́run hàn wọ́n àti iṣẹ́ tí wọn yóò máa ṣe Sà àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ yàn wọ́n se olórí lórí ẹgbẹ̀rún-ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún-ọgọ́rùn-un, àádọ́ta-àádọ́ta àti mẹ́wàá-mẹ́wàá Jẹ́ kí wọn ó máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ni gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn mú ẹjọ́ tí ó bá nira fún wọn láti dá tọ̀ ọ́ wá kí wọn kí ó máa dá ẹjọ́ kéékèèkéé Èyí ni yóò mú iṣẹ́ rẹ rọrùn, wọn yóò sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí ìdájọ́ ṣíṣe Bí ìwọ bá ṣe èyí, bí Ọlọ́run bá sì fi àṣẹ sí i fún ọ bẹ́ẹ̀, àárẹ̀ kò sì ní tètè mu ọ, àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò sì padà lọ ilé wọn ni ìtẹ́lọ́rùn Mósè fetísílẹ̀ sí àna rẹ̀, ó sì ṣe ohun gbogbo tí ó wí fún un Mósè sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kun ojú òsùwọ̀n nínú gbogbo Ísírẹ́lì ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rùn, ọgọ́rùn ún ọgọ́rùn ún, àádọ́ta-àádọ́ta, àti mẹ́wàá-mẹ́wàá Wọ́n sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ní ìgbà gbogbo Wọ́n sì ń mú ẹjọ́ tó le tọ Mósè wá ṣùgbọ́n wọ́n ń dá ẹjọ́ tí kò le fún rawọn Mósè sì jẹ́ kí àna rẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀, Jẹ́tírò sì padà sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀ Ní Orí Òkè Ṣínáì Ní oṣù kẹ́ta tí àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì, ni ọjọ́ náà gan an ni wọ́n dé ihà Ṣínáì Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbéra kúrò ní Réfídímù, wọ́n wọ ijù Ṣínáì, wọ́n sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀ ní iwájú òkè Ṣínáì Mósè sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ Olúwa sì ké pè é láti orí òkè náà wá pé, Èyí ni ìwọ yóò sọ fún ilé Jákọ́bù àti ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Éjíbítì, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì Nísinsìn yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́rán sí mi dé ojú àmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mu mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀ èdè yóòkù lọ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀ èdè mímọ́ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Mósè sì tọ àwọn ènìyàn wá, ó sí pe àwọn àgbààgbà láàárin àwọn ènìyàn jọ Ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ ti Olúwa pàṣẹ fún un láti sọ ni iwájú wọn Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, Àwa yóò se ohun gbogbo ti Olúwa wí Mósè sì mú ìdáhùn wọn padà tọ Olúwa lọ Olúwa sọ fún Mósè pé, Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu síṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́ Nígbà náà ni Mósè sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún Olúwa Olúwa sì wí fún Mósè pé, Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn Kí wọn kí ó sì múra di ọjọ́ kẹ́ta, nítorí ni ọjọ́ náà ni Olúwa yóò sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Ṣínáì ni ojú gbogbo àwọn ènìyàn Kí ìwọ kí ó se ààlà fún àwọn ènìyàn, ibi tí wọn lè dé dúró, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, Ẹ ṣọ́ra! Ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ máa tilẹ̀ fi ọwọ́ kan etí ààlà rẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà yóò kú Ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án, ẹni tí ó fi ọwọ́ kan òkè náà a ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta a ní ọfà, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko Òun kì yóò wà láàyè Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá Mósè sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn Ó sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, Ẹ múra sílẹ̀ di ọjọ́ kẹta Ẹ má ṣe bá aya yín lòpọ̀ Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹ́ta, àrá àti mọ̀nàmọ́ná sì wà pẹ̀lú ìkùùkuu tí ó sú dudu ní orí òkè, ìpè ńlá sì dún kíkan kíkan tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ó wà ni ibùdó wárìrì Mósè sì kó àwọn ènìyàn tí ó jáde láti ibùdó wá pàdé Ọlọ́run, wọ́n dúró nítòsí òkè Èéfín sì bo òkè Sínáì nítorí Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ nínú iná Èéfín náà sì ń ru sókè bí èéfín iná ìléru, gbogbo òkè náà sì mì tìtì Ohùn ìpè sì ń rinlẹ̀ dòdò Mósè sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì fi àrá dá a lóhùn Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Ṣínáì, o sì pe Mósè wá sí orí òkè náà Mósè sì gun orí òkè Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ̀kalẹ̀, kí ó sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí wọn má ṣe fi tipátipá wá ọ̀nà láti wo Olúwa , bí wọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn yóò ṣègbé Kódà àwọn àlùfáà tí ó ń wá ṣíwájú Olúwa gbọdọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ Olúwa yóò kọ lù wọ́n Mósè wí fún Olúwa pé, Àwọn ènìyàn kì yóò lè wá sí orí òkè Ṣínáì, nítorí ìwọ fúnrarẹ ti kìlọ̀ fún wa pé, Ṣe ààlà yí òkè ká, kí o sì yà á sí mímọ́   Olúwa sì wí fún Mósè pé, Sọ̀kalẹ̀ lọ, mú Árónì gòkè wá pẹ̀lú rẹ Ṣùgbọ́n kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn má ṣe fi tipátipá gòkè tọ Olúwa Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò kọlù wọ́n Mósè ṣọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ènìyàn lọ Ó sì sọ ohun tí Olúwa wí fún wọn Ìbí Mósè Ó sì ṣe, ọkùnrin ará ilé Léfì kan fẹ́ ọmọbìnrin ará Léfì kan ni ìyàwó Obìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan Nígbà tí ó rí í pé ọmọ náà rẹwà, ó gbé ọmọ náà pamọ́ fún oṣù mẹ́ta Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé pápírúsì hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà ati òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú esùnsún ni etí odò Náílì Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà Nígbà náà ni ọmọbìnrin Fáráò sọ̀kalẹ̀ wá sí etí odò Náílì láti wẹ̀, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ń rìn ni etí bèbè odò Ó sì ri apẹ̀rẹ̀ náà ni àárin esùnsún, ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin kan láti lọ gbé e wá, ó sí i, ó sì rí ọmọ náà Ọmọ náà ń sunkún, àánú ọmọ náà sì ṣe é Ó wí pé Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hébérù ni èyí Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Fáráò pé Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Hébérù wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà Ó sì dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni lọ Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá, Ọmọbìnrin Fáráò sì wí fún un pé, Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀ Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Fáráò wá, ó sì di ọmọ rẹ̀ Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mósè, ó wí pé Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mósè ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, O ri ará Éjíbítì tí ń lu ará Ébérù, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ Ó wo ìhín, ó wo ọ̀hún, nígbà tí kò rí ẹnìkankan, ni ó bá pa ará Éjíbítì náà, ó sì bò ó mọ́ inú iyanrìn Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Hébérù méjì tí wọ́n ń jà Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Hébérù arákùnrin rẹ Ọkùnrin náà sì dáhùn pé Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídájọ́ lórí wa Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ṣe pa ará Éjíbítì Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mósè, ó rò nínú ara rẹ̀ pé ó ní láti jẹ́ wí pé ohun tí mo ṣe yìí ti di mímọ̀ Nígbà ti Fáráò sì gbọ́ nípa èyí, ó wá ọ̀nà láti pa Mósè, ṣùgbọ́n Mósè sá kúrò ní àrọ́wọ́tó o Fáráò, ó lọ sí Mídíánì láti máa gbé, nígbà tí ó dé bẹ̀, ó jókòó ni ẹ̀bá a kànga kan Ó sì ṣe, àlùfáà Mídíánì kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn Àwọn darandaran kán wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Mósè dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi Nígbà ti àwọn ọmọbìnrin náà padà dé ọ̀dọ̀ Rúẹ́lì baba wọn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé Èéṣe tí ẹ̀yin fi tètè dé ni òní Wọ́n dá a lóhùn pé, Ará Éjíbítì kan ni ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn darandaran, ó tilẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fa omi àti láti fún agbo ẹran ní omi Ó sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, Níbo ni ó wà Èéṣe ti ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀ Ẹ pè é wá jẹun Mósè gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ẹni tí o fi Sípórà, ọmọbìnrin rẹ̀ fún Mósè láti fi ṣe aya Ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gésómù, ó wí pé Èmi ń ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ọba Éjíbítì kú Àwọn ará Ísírẹ́lì ń kérora ní oko ẹrú wọn, wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ nítorí oko ẹrú tí wọ́n wà, igbe wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ọlọ́run gbọ́ igbe wọn, ó sì rántí Májẹ̀mu rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísáákì àti pẹ̀lú Jákọ́bù Nítorí náà, Ọlọ́run bojú wo àwọn ará Ísírẹ́lì, Ó sì wà láti gbà wọ́n sílẹ̀ Òfin Mẹ́wàá Olúwa sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde ni ilẹ̀ Éjíbítì, jáde ni oko ẹrú Ìwọ kò gbọdọ̀ ní Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara rẹ ní àwòrán ohun kóhun tí ń bẹ ní òkè ọ̀run tàbí tí ń bẹ ní ayé, tàbí tí ń bẹ ní ìṣàlẹ̀ omi Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀sẹ̀ baba wò lára ọmọ láti ìran kìn-ín-ní títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi Ṣùgbọ́n mo ń fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹ̀rún ìran nínú àwọn tí ó fẹ́ mi tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́ Ìwọ kò gbọdọ̀ pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ ní asán, nítorí Olúwa kì yóò ka àwọn tí ó ń pe orúkọ rẹ̀ ní asán bí aláìlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀run Rántí ọjọ́ ìsinmi kí o sì yà á sí mímọ́ Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ, Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ Nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kiṣẹ́ kan ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkunrìn àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin tàbí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, tàbí ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ tó wà ní nínú ibodè rẹ Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé, òkun àti gbogbo nǹkan tí ó wà nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó sinmi ní ọjọ́ keje Nítorí náà ni Olúwa ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́ Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ bá a le pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ Ìwọ kò gbọdọ̀ pa ènìyàn Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí ilé aládùúgbò rẹ Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí aya aládùúgbò rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin tàbí sí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti aládùúgbò rẹ Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n sìgàsìgà fún ìbẹ̀rù Wọ́n wí fún Mósè pé, Ìwọ fúnraàrẹ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́ Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnraarẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú Mósè sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, Ẹ má bẹ̀rù Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe sẹ̀ Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mósè súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà Olúwa sì sọ fún Mósè pé, Sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ará Ísírẹ́lì Ẹ̀yin ti rí i fúnraayín bí èmi ti bá a yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín  Pẹpẹ erùpẹ̀ ni kí ìwọ mọ fún mi Ní orí pẹpẹ yìí ni kí ìwọ ti máa rú ẹbọ sísun rẹ sí mi àti ẹbọ àlàáfíà rẹ, àgùntàn rẹ, ewúrẹ́ àti akọ màlúù rẹ Ní ibi gbogbo tí mo gbé fi ìrántí orúkọ mi sí, èmi yóò sì máa tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bùkún ọ níbẹ̀ Bí ìwọ bá ṣe pẹpẹ òkúta fún mi, má ṣe fi òkúta tí a se lọ́sọ̀ọ́ kọ́ ọ, nítorí bí ìwọ bá lo ohun ọnà rẹ lorí rẹ̀, ìwọ sọ ọ di àìmọ́ Ìwọ kò gbọdọ̀ gun àkàsọ̀ lọ sí ibi pẹpẹ mi, kí àwọn ènìyàn má ba à máa wo ìhòòhò rẹ láti abẹ́ aṣọ tí ìwọ wọ̀ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ sí ibi pẹpẹ Òfin nípa Ìwọ̀fà Wọ̀nyí ni àwọn òfin tí ìwọ yóò gbé sí iwájú wọn Bí ìwọ bá yá ọkùnrin Hébérù ní ìwẹ̀fà, òun yóò sìn ọ́ fún ọdún Mẹ́fà Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, òun yóò lọ ni òmìnira láìsan ohunkóhun padà Bí ó bá wá ní òun nìkan òun nìkan náà ni yóò padà lọ ní òmìnira ṣùgbọ́n tí ó bá mú ìyàwó wá, ó ní láti mú ìyàwó rẹ̀ padà lọ Bí olówó rẹ̀ bá fún un ní aya, tí aya náà sì bímọ ọkùnrin àti obìnrin, aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ ti olówó rẹ̀, yóò sì lọ ní òmìnira ní òun nìkan Bí ìwọ̀fà náà bá sọ gbangba pé, mo fẹ́ràn olówó mi, ìyàwó mi àti àwọn mi èmi kò sì fẹ́ ẹ́ gba òmíràn mọ́ Nígbà náà ni olówó rẹ̀ yóò mu wá sí iwájú ìdàjọ́ Òun yóò sì mú un lọ sí ẹnu ọ̀nà tàbí lọ sí ibi òpó, yóò sì fi ìlutí lu etí rẹ̀, òun yóò sì máa sin olówó rẹ̀ títí ayé Bí ọkùnrin kan bá ta ọmọbìnrin rẹ̀ bí ìwẹ̀fà, ọmọbìnrin yìí kò ní gba òmìnìra bí i ti ọmọkùnrin Bí òun kò bá sì tẹ́ olówó rẹ̀ lọ́rùn, ẹni tí ó fẹ́ ẹ fún ara rẹ̀, yóò jẹ́ kí wọn ó rà á padà, òun kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á bí ẹrú fún àwọn èniyàn orílẹ̀ èdè mìíràn, nítorí pé òun ni kò se ojúse rẹ̀ pẹ̀lú ìwẹ̀fà náà Bí ó bá fẹ́ ẹ fún ọmọkùnrin rẹ̀, kò ní máa lò ó bí ìwẹ̀fà mọ́, ṣùgbọ́n yóò máa ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ obìnrin Bí ó bá fẹ́ obìnrin mìíràn, kò gbọdọ̀ kùnà ojúṣe rẹ̀ nípa fífún un ní oúnjẹ àti aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kùnà ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ sí aya Bí ó bá kùnà láti ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí fún un, òun yóò lọ ní òmìnira láìsan owó kankan padà Ẹnikẹ́ni tí ó bá lu arákùnrin rẹ̀ pa, pípa ni a ó pa á Ṣùgbọ́n bí kò bá mọ̀ ọ́n mọ̀ pa á, tí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run ni, òun yóò lọ sí ibi tí èmi yóò yàn fún un Ṣùgbọ́n tí ó bá arákùnrin rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀tàn pa á Ẹ mú un kúrò ní iwájú pẹpẹ mi kí ẹ sì pa á Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á Ẹnikẹ́ni ti ó bá ji ènìyàn gbé, tí ó sì tà á tàbí tí ó fi ì pamọ́, pípa ni a ó pa á Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á Bí àwọn ọkùnrin méjì bá ń jà, ti ọ̀kan sọ òkúta tàbí fi ẹ̀ṣẹ́ lu ẹnìkejì rẹ̀, tí ó sì pa á lára, ti irú ìpalára bẹ́ẹ̀ mu kí ó wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn, Ẹni tó lu ẹnìkejì rẹ̀ kò ní ní ẹ̀bi, níwọ̀n ìgbà ti ẹni tí a lù bá ti lè dìde, tí ó sì lé è fi ọ̀pá ìtilẹ̀ ní ọwọ rẹ̀ rìn káàkiri Ẹni náà ni láti san owo ti ó fi tọ́jú ara rẹ̀ padà fún un, lẹ́yìn ìgbà tí ara rẹ̀ bá ti yá tan pátápátá Bí ọkùnrin kan bá fi ọ̀pá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrubìnrin rẹ̀, ti ẹrú náà sì kú lójú ẹṣẹ̀, a ó fi ìyà jẹẹ́ Ṣùgbọ́n a kò ní fi ìyà jẹ̀ ẹ́, ti ẹrú náà bá yè, tí ó dìde lẹ́yìn ọjọ́ kan tàbí méjì, nítorí ẹrú náà jẹ́ dúkìá rẹ̀ Bí àwọn ènìyàn ti ń jà bá pa aboyún lára, tí aboyún náà bá bimọ láìpé ọjọ́, ṣùgbọ́n ti kò sí aburú mìíràn mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ẹni ti ó fa ìpalára yìí yóò san iyekíye ti ọkọ aboyún náà bá béèrè fún, bí ilé ẹjọ́ bá se gbà láàyè gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn Ṣùgbọ́n bí ìpalára náà bá yọrí sí ikú aboyún náà, pípa ni a ó pa ẹni ti ó fa ikú aboyún náà Ojú fún ojú, eyín fún eyín, ọwọ́ fún ọwọ́, ẹṣẹ̀ fún ẹṣẹ̀, ìjóná fún ìjóná, ọgbẹ́ fún ọgbẹ́, ìnà fún ìnà Bí ọkùnrin kan bá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ní ojú, ti ojú náà sì fọ́, ó ni láti jẹ́ kí ẹrú náà lọ ní òmìnira fún ìtanràn ojú rẹ̀ ti ó fọ́ Bí ó bá sì lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ti eyín rẹ̀ fi ká, ó ni láti jẹ́ kí ó lọ ní òmìnira ni ìtanran fún eyín rẹ̀ tí ó ká Bí akọ màlúù bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin kan pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀ Ṣùgbọ́n a kò ní dá ẹni tí ó ni akọ màlúù náà lẹ́bi, ọrùn rẹ̀ yóò sì mọ́ Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo ti akọ màlúù náà ti máa ń kan ènìyàn, tí a sì ti ń kìlọ̀ fún olówó rẹ̀, ti olówó rẹ̀ kò sì mú un so, tí ó bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a ó sì pa olówó rẹ̀ pẹ̀lú Bí àwọn ará ilé ẹni tí ó kú bá béèrè fún owó ìtanràn, yóò san iye owó tí wọ́n bá ní kí ó san fún owó ìtanràn láti fi ra ẹ̀mí araarẹ̀ padà Bí akọ màlúù bá kan ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin pa, a ó se gẹ́gẹ́ bí ofin yìí ti là á kalẹ̀ Bí akọ màlúù bá kan ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin pa, olówó rẹ̀ yóò san ọgbọ̀n sékélì fàdákà fún ẹni tó ni ẹrú, a ó sì sọ akọ màlúù náà ni okúta pa Bí ọkùnrin kan bá sí kòtò sílẹ̀ láìbò tàbí kí ó gbẹ́ kòtò sílẹ̀ láìbò, tí màlúù tàbi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá se bẹ́ẹ̀ bọ́ sínú kòtò náà Ẹni tí ó ni kòtò yóò san owó àdánù yìí fún ẹni tí ó ni ẹran Òkú ẹran náà yóò sì di tirẹ̀ Bí akọ màlúù ọkùnrin kan bá pa akọ màlúù ẹlòmíràn lára tí ó sì kú, wọn yóò ta akọ màlúù tó wà láàyè, wọn yóò sì pín owo èyí ti wọn tà àti ẹran èyí tí ó kú dọ́gbadọ́gba Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo tí akọ màlúù náà máa ń kan òmíràn, tí olówó rẹ̀ kò sì mú un so, olówó rẹ̀ yóò san ẹran dípò ẹran Ẹran tí ó kú yóò sì jẹ́ tirẹ̀ Ìdáàbò bo ohun ìní Bí ọkùnrin kan bá jí akọ màlúù tàbí àgùntàn, tí ó sì pa á tàbí tà á Ó gbọdọ̀ san akọ màlúù márùn ún padà fún ọ̀kan tí ó jí, àti àgùntàn mẹ́rin mìíràn fún ọ̀kan tí ó jí Bí a bá mú olè níbi ti ó ti ń fọ́lé, ti a sì lù ú pa, ẹni tí ó lù ú pa náà kò ní ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ Ṣùgbọ́n ti ó bá ṣẹlẹ̀ ni ojú ọ̀sán, a ó kà á si ìpànìyàn Ọkùnrin ti ó lù ú pa náà yóò ni ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ Olè gbọdọ̀ san ohun tí ó jí padà Ṣùgbọ́n tí kò bá ni ohun ti ó lè fi san án padà, a ó tà á, a ó sì fi sanwó ohun tí ó jí gbé padà Bí a bá rí ẹran tí ó jí gbé náà ni ọwọ́ rẹ̀ ní ààyè ìbá se akọ màlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àgùntàn, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì Bí ọkùnrin kan bá ń bọ́ ẹran ọ̀sìn rẹ̀ lórí pápá tàbí nínú ọgbà àjàrà, tí ó sì jẹ́ kí ó lọ jẹ nínú oko ẹlòmíràn, a ó mú kí ó san ohun ti ẹran rẹ̀ jẹ padà pẹ̀lú èyí tí ó dára jù nínú oko tàbí nínú ọgbà rẹ̀ Bí iná bá ṣẹ́ tí ó kán lu igbó tí ó sì jó àká ọkà tàbí gbogbo oko náà, ẹni tí iná ṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ yóò san ohun tí ìná ti ó ṣẹ́ jó padà Bí ọkùnrin kan bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní fàdákà tàbí ohun èlò fún ìtọ́jú, ti wọ́n sì jí gbé lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí a bá mú irú olè bẹ́ẹ̀, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì Ṣùgbọ́n ti a kò bá rí olè náà mú, ẹni tí ó ni ilé náà yóò fi ara hàn níwájú ìdájọ́ láti jẹ́ kí a mọ̀ bí oun fúnrarẹ̀ ni ó gbé ohun ti ó sọnù náà Bí ẹnìkan bá ni akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, aṣọ tàbí ohun ìní mìíràn tí ó sọnù ní ọ̀nà ti kò bá òfin mu, tí a sì rí ẹni ti ó sọ pé òun ni ó ní ín, àwọn méjèèjì yóò mú ẹjọ́ wọn wá sí iwájú adájọ́ Ẹnikẹ́ni tí adájọ́ bá dá lẹ́bi yóò san án ni ìlọ́po méjì padà fún ẹnìkejì rẹ̀ Bí ẹnikẹ́ni bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, akọ màlúù, àgùntàn tàbí ẹranko mìíràn láti bá oun tọ́jú rẹ̀, tí ó sì kú, tàbí tí ó fi ara pa, tàbí tí a jí gbé, níbi tí kò ti sí ẹni tí o ṣe àkíyèsí Wọn yóò búra sí ọ̀rọ̀ náà láàrin ara wọn ni iwájú Olúwa láti fihàn pé òun kò ní ọwọ́ nínú sísọnù ohun ọ̀sìn náà, olóhun gbọdọ̀ gba bẹ́ẹ̀, a kò sì ní san ohunkóhun fún un Ṣùgbọ́n ti wọ́n bá ji ẹranko náà gbé ni ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, yóò san ẹ̀san padà fún un Bí ẹranko búburú bá fà á ya, ó ní láti mú àyakù ẹran náà wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, kò sì ní san ẹran náà padà Bí ẹnìkan bá sì yá ẹranko lọ́dọ aládúgbò rẹ̀, tí ẹranko náà sì fi ara pa, tàbí kí ó kú nígbà tí ẹni tí ó ni ín kò sí nítòòsí O gbọdọ̀ san án padà Ṣùgbọ́n ti ó bá jẹ́ wí pé ó háyà ẹranko náà ni, kò ní láti san ẹ̀san padà, owó tí ó fi háyà ẹranko yìí ni yóò fi tan àdánù ẹranko tí ó kú Bí ọkùnrin kan bá fi àrékérekè mú wúndíá kan, ẹni tí kò pinnu láti fẹ́, tí ó sì bá a lòpọ̀, yóò san owó orí rẹ̀, yóò sì fi ṣe aya rẹ̀ Bí baba ọmọbìnrin náà bá kọ̀ jálẹ̀ láti fi fún un ní aya, ó ni láti san owó tó tó owó orí rẹ̀, fún fí fẹ́ ẹ ní wúndíá Má ṣe jẹ́ kí àjẹ́ kí ó wà láàyè Ẹnikẹ́ni ti ó bá bá ẹranko lopọ̀ ní a ó pa Ẹnikẹ́ni ti ó bá rúbọ sí òrìṣà yàtọ̀ sí Olúwa nìkan, ni a ó yà sọ́tọ̀ fún ìparun Ẹ má ṣe fi ìyà jẹ àlejò tàbí ni wọ́n lára, nítorí ìwọ pẹ̀lú ti jẹ́ àlejò ni ilẹ̀ Éjíbítì rí Má ṣe yan opó tàbí ọmọ òrukàn jẹ Bí ìwọ bá se bẹ́ẹ̀, bí wọn bá ké pè mi Èmi yóò sì gbọ́ ohùn igbe wọn Ìbínú mi yóò ru sókè Èmi yóò sì fi idà pa ọ Ìyàwó rẹ yóò di opó, àwọn ọmọ rẹ yóò sì di aláìní baba Bí ìwọ bá yá ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn mi tí ìyà ń jẹ láàrin yín lówó, má ṣe dàbí ayánilówó, kí o má sì gba èlé Bí ìwọ bá gba aṣọ aládùúgbò rẹ ni ẹ̀jẹ́, ìwọ gbọdọ̀ fún un padà kí òòrùn tó ó wọ̀, Nítorí aṣọ yìí nìkan ní ó ní ti ó lè fi bo àṣírí ara Kí ni ohun mìíràn ti yóò fi sùn Nígbà ti ó bá gbé ohun rẹ̀ sókè sími, èmi yóò gbọ́ nítorí aláàánú ni èmi Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run tàbí sẹ́ èpè lé orí ìjòyé àwọn ènìyàn rẹ Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́ra láti mú ọrẹ wá fún mi láti inú ire oko rẹ àti láti inú wáìnì rẹ Àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin ni ìwọ yóò fi fún mi Ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú agbo màlúù rẹ àti agbo àgùntàn rẹ Jẹ́ kí wọn wà lọ́dọ̀ ìyá wọn fún ọjọ́ méje, kí ìwọ kí ó sì fi wọ́n fún mi ní ọjọ kẹjọ Ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mímọ́ mi Nítorí náà má ṣe jẹ ẹran ti ẹranko búburú fàya ẹ fi fún ajá jẹ Òfin Òdodo àti Àánú Ìwọ kò gbọdọ̀ tan ìròyìn èké kalẹ̀ Ìwọ kò gbọdọ̀ ran ènìyàn búburu lọ́wọ́ láti jẹ́rìí èké Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀pọ̀ ènìyàn láti se aburú Nígbà tí ìwọ bá jẹ́rìí sí ẹjọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po nípa gbígbé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ènìyàn Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúṣáájú sí talákà nínú ẹjọ́ rẹ̀ Bí ìwọ bá se alábàápàdé akọ màlúù tàbí akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ọ̀ta rẹ tí ó sinà lọ, rí i dájú pé o mú un padà wá fún un Bí ìwọ bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnìkan tí ó koríra rẹ tí ẹrù subú lé lórí, má ṣe fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ rí i dájú pé o ran án lọ́wọ́ nípa rẹ Ìwọ kò gbọdọ̀ du aláìní ní ìdájọ́ òdodo Má ṣe lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn èké, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tàbi olódodo ènìyàn, nítorí èmi kò ní dá ẹlẹ́bí láre Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń fọ àwọn tó ríran lójú, a sì yí ọ̀rọ̀ olódodo po Ìwọ kò gbọdọ pọ́n àlejò kan lójú sa ti mọ inú àlejò, nítorí ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ Éjíbítì Ní ọdún mẹ́fà ni ìwọ yóò gbin oko rẹ, ìwọ yóò sì kóre èso rẹ̀ Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, jẹ́ kí ilẹ̀ náà wà ní àìkọ àti ní àìlò, jẹ́ kí ilẹ̀ náà kí ó sinmi Nígbà náà ni talákà láàrin yín yóò rí oúnjẹ láti ibẹ̀ Ẹranko igbó yóò sì jẹ èyí tí wọ́n fi sílẹ̀ Ìwọ ṣe bákan náà pẹ̀lú ọgbà-àjàrà rẹ àti ọgbà Olífì rẹ Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì sinmi ní ọjọ́ keje, kí akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ bá à lè ní ìsinmi, kí a sì tú ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àlejò ti ń gbé ni ilé rẹ lára Ẹ máa sọ́ra, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo wí fún un yín Ẹ má se pe orúkọ òrìṣà, kí a má se gbọ́ orúkọ wọn ní ẹnu yín Ní ìgbà mẹ́ta ni ìwọ yóò se àjọ̀dún fún mi nínú ọdún Ṣe àjọ̀dún àkàrà àìwú jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje, bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ Ṣe èyí ní àkókò tí a ti yàn ní oṣù Ábíbù, nítorí ni oṣù yìí ni ìwọ jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo Ṣe àjọ̀dún ìkórè pẹ̀lú èso àkọ́so ọ̀gbìn oko rẹ Ṣe àjọ̀dún àkójọ oko rẹ ní òpin ọdún, nígbà tí ìwọ bá kó irè oko rẹ jọ tan Ní ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ọkùnrin yín yóò máa wá fi ara hàn ní iwájú Olúwa Ọlọ́run Ìwọ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ sí mi ti òun ti búrẹ́di tó ní ìwúkàrà Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rá ẹbọ àjọ mi ni kò gbọdọ̀ kù títí di òwúrọ̀ Mú èso àkọ́so ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ Ìwọ kò gbọdọ̀ fi omi ọmú ìyá ewúrẹ́ bọ ọmọ ewúrẹ́ Kíyèsí èmi rán ańgẹ́lì kan lọ ní iwájú rẹ, láti ṣọ́ ọ ni ọ̀nà àti láti mú ọ dé ibi ti mo ti pèsè sílẹ̀ fún Fi ara bálẹ̀, kí o sì fetísílẹ̀ sí i, kí o sì gba ohùn rẹ̀ gbọ́ má ṣe sọ̀tẹ̀ sí i, nítorí kò ní fi àìsedédé yín jin yín, orúkọ mi wà lára rẹ̀ Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí ohùn rẹ̀ tí ẹ sì se ohun gbogbo ti mo ní kí ẹ ṣe, èmi yóò jẹ́ ọ̀tá àwọn ọ̀tá yín Èmi yóò sì fóòrò àwọn tí ń fóòrò yín Ańgẹ́lì mi yóò lọ níwájú ẹ, yóò sì mú ọ dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Ámórì, Hitì, Párísì, Kénánì, Hífi àti Jébúsì, èmi a sì ge wọn kúrò Ìwọ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún òrìṣà wọn, bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, tàbí kí ẹ tẹ̀lé ìṣe wọn Kí ìwọ kí ó si wó wọn lulẹ̀, kí ìwọ kí ó sì fọ́ ère òkúta wọ́n túútúú Ẹ̀yin yóò sí máa sìn Olúwa Ọlọ́run yin, òun yóò si bù sí oúnjẹ rẹ Èmi yóò mú àìsàn kúrò láàrin rẹ Oyún kò ní bàjẹ́ lára obìnrin kan, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan kì yóò yàgàn ni ilẹ̀ rẹ Èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mi gígùn Èmi yóò rán ẹ̀rù mi lọ ṣáájú rẹ, ìdàrúdàpọ̀ yóò sì wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ bá da ojú kọ Èmi yóò mú kí àwọn ọ̀ta rẹ yí ẹ̀yìn padà sí ọ, kí wọn sì sá ní iwájú rẹ Èmi yóò rán oyin ṣáájú rẹ láti lé àwọn ará Hífì, Kénánì àti Hítì kúrò ni ọ̀nà rẹ Ṣùgbọ́n, èmi kò ni lé gbogbo wọn jáde ni ọdún kan soso, ki ilẹ̀ náà má ba à di ahoro, àwọn ẹranko búburú yóò sì ti pọ̀ jù fún ọ Díẹ̀díẹ̀ ni èmi yóò máa lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ, títí ìwọ yóò fi pọ̀ tó láti gba gbogbo ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ìní Èmi yóò fi ìdí òpin ààlà ilẹ̀ rẹ lélẹ̀ láti etí òkun pupa títí dé òkun àwọn ara Fílístínì, láti aṣálẹ̀ títí dé etí odò Éfúrétì Èmi yóò fa àwọn ènìyàn ti ń gbé ilẹ̀ náà lé ọ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ Ìwọ kò gbọdọ̀ dá májẹ̀mú kankan pẹ̀lú wọn tàbí pẹ̀lú àwọn òrìṣà wọn Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn gbé ni ilẹ̀ rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò mú ọ dẹ́ṣẹ̀ sí mi nítorí bí ìwọ bá sin òrìṣà wọn, èyí yóò jẹ́ ìdẹkùn fun ọ nítóòtó Ìfimúlẹ̀ Májẹ̀mú Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Gòkè tọ Olúwa wá, ìwọ àti Árónì, Nádábú àti Ábíhù àti àádọ́rin àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré Ṣùgbọ́n Mósè nìkan ṣoṣo ni yóò súnmọ́ Olúwa àwọn tókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò gbọdọ̀ gòkè wá pẹ̀lú rẹ̀ Nígbà ti Mósè lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ àti òfin Olúwa , wọ́n wí ní ohùn kan pé, Gbogbo ohun ti Olúwa wí ni àwa yóò ṣe Nígbà náà ni Mósè kọ gbogbo ohun tí Olúwa sọ sílẹ̀ Ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mọ pẹpẹ ni ẹsẹ̀ òkè náà Ó se ọ̀wọ́n òkúta méjìlá Èyí ti ó dúró fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Ísírẹ́lì, wọ́n sì rúbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si Olúwa Mósè bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn Wọ́n dáhùn pé, Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí Olúwa wí Àwa yóò sì gbọ́ràn Nígbà náà ni Mósè gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí Mósè àti Árónì, Nádábù àti Ábíhù àti àádọ́rin àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì gòkè lọ Wọ́n sì rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì Ní abẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta sáfírè ṣe wà Èyí ti ó mọ́ niṣínniṣín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnraarẹ̀ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wọ̀nyí wọ́n ri Ọlọ́run, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu Olúwa sì sọ fún Mósè pé, Gòkè wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí o sì dúró níhín-ín Èmi yóò sì fún ọ ní òkúta ìkọ̀wé pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí mo ti kọ sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn Nígbà náà ni Mósè jáde lọ pẹ̀lú Jọsúà arákùnrin rẹ̀ Mósè lọ sí orí òkè Ọlọ́run Ó sì wí fún àwọn àgbààgbà pé, Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsìí, Árónì àti Húrì ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnikan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ Nígbà tí Mósè gun orí òkè lọ, ìkúúkùù bo orí òkè náà Ògo Olúwa sì wà ní orí òkè Ṣí náì Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni Olúwa kọ sí Mósè láti inú ìkùùkuu náà wá Ni ojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ògo Olúwa náà dà bí iná ajónirun ni orí òkè Nígbà náà ni Mósè wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru Ọrẹ-Ẹbọ Fún Àgọ́ Olúwa sì wí fún Mósè pé, Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọn mú ọrẹ wá fún mi ìwọ yóò gba ọrẹ náà fún mi ni ọwọ́ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ti ọkàn rẹ bá fẹ́ láti fi fún mi Wọ̀nyí ni ọrẹ ti ìwọ yóò gbà ni ọwọ́ ọ wọn wúrà, fàdákà, idẹ, aṣọ aláwọ̀ aró, aṣọ aláwọ̀ aró-fẹ́ẹ́rẹ́, aṣọ aláwọ̀ òdòdó, aṣọ funfun-láú, ìrun ewúrẹ́ Awọ àgbò tí a rẹ ní pupa àti awọ ewúrẹ́-dò igi kásíà Òróró olífì fún iná títàn, òróró olóórùn dídùn fún ìtasórí àti fún tùràrí olóórùn dídùn, àti òkúta oníkì àti òkúta olówó iyebíye ti a fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí ara ẹ̀wù éfódi àti ẹ̀wù ìgbàyà Nígbà náà ni ìwọ yóò jẹ́ kí wọn kọ́ ibi mímọ́ fún mi Èmi yóò sì máa gbé ní àárin wọn Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí ti mo fi hàn ọ́, nípa àpẹẹrẹ àgọ́, àti àpẹẹrẹ gbogbo ohun èlò inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe é Kí wọn kí ó fi igi kasíà ṣe àpótí, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀, kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ Bo orí rẹ̀ pẹ̀lú ojúlówó wúrà, bò ó ni inú àti ìta kí o sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká Ṣe òrùka wúrà mẹ́rin fún un Kí o sì so wọ́n mọ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì Fi igi kaṣíà ṣe òpó mẹ́rin, kí o sì fi wúrà bò ó Fi òpó náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí náà láti fi gbé e Òpó náà yóò wá nínú òrùka lára àpótí ẹ̀rí a ko ní yọ wọ́n kúrò Nígbà náà ni ìwọ yóò fi ẹ̀rí ti èmi yóò fi fún ọ sínú àpótí náà Ojúlówó wúrà ni kí o fi se ìtẹ́ àánú ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní fífẹ̀ Fi wúrà tí a lù se kérúbù méjì sí igun ìtẹ́-àánú Ṣe kérúbù kan sí igun kìn-ín-ní àti kérúbù kejì sí igun kejì kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì Apá àwọn kérúbù náà yóò wà ní gbígbé sókè, tí wọn yóò sì fi apá wọn se ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́ Gbé ọmọrí orí àpótí ẹ̀rí kí o sì fi ẹ̀rí èyí tí èmí yóò fi fún ọ sínú àpótí ẹ̀rí Níbẹ̀, ni òkè ìtẹ́, ní àárin kérúbù méjèèjì ti ó wà ni orí àpótí ẹ̀rí ni èmi yóò ti pàdé rẹ, ti èmi yóò sì fún ọ ní àwọn òfin mi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Fi igi kaṣíà kan tábílì ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní gíga Kí o fi ojúlówó wúrà bò ó, kí o sì mọ wúrà yíká Bákan náà, mọ etí rẹ̀ yíká pẹ̀lú wúrà níwọ̀n fífẹ ìbúwọ́, kí o sì fi wúrà mímọ́ sí ibí orúka rẹ Ṣe òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, kí o so ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mọ́ igun ẹsẹ̀ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan Òrùka náà ko gbọdọ̀ jìnnà sí etí rẹ̀, kí ó lè gbá òpó mú nígbà tí a bá ń gbé tábìlì náà Fi igi kaṣíà ṣe òpó, fi wúrà bò wọ́n, kí o sì máa fi wọ́n gbé tábìlì náà Fi ojúlówó wúrà se àwo àti ṣíbí rẹ̀, kí o sì ṣe àwokòtò àti ago pẹ̀lú fún dída ọrẹ jáde Gbé àkàrà ìfihàn sí orí tabílì yìí, kí ó le wà ní iwájú mi ni gbogbo ìgbà Mú ojúlówó wúrà, lù ú dáradára, kí o sì fi ṣe ọ̀pá fìtílà, ìsàlẹ̀ àti apá rẹ̀, kọ́ọ̀bù rẹ̀ ti ó dàbí òdòdó, ìṣọ àti ìtànná rẹ̀ yóò jẹ́ ara kan náà pẹ̀lú rẹ̀ Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì Kọ́ọ̀bù mẹ́ta tí a se bí òdòdó alímọ́ńdì tí ó sọ tí ó sì tanná ni yóò wà ni apá kan, mẹ́ta yóò sì wà ní apá kejì, àti bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó jáde lára ọ̀pá fìtílà Ní ara ọ̀pá fìtílà ni kọ́ọ̀bù mẹ́rin ti a se gẹ́gẹ́ bí òdòdó alímọńdì ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà Ìṣọ kan yóò wà lábẹ́ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, ìṣọ kejì lábẹ́ ẹ̀ka méjì kejì, ìṣọ kẹta ní abẹ́ ẹ̀ka mẹ́ta kẹta ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀ Ìṣọ àti ẹ̀ka yóò di ara kan náà pẹ̀lú òpó fìtílà ti a fi ojúlówó wúrà ti a lù ṣe Nígbà náà ni ìwọ yóò se fítílà méje Ìwọ yóò sì gbe ka orí rẹ̀, kí wọn bá a lè tan iná sí iwájú rẹ̀ Ike ọ̀pá àbẹ́là àti ọpọ́n agogo gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí a fi ojúlówó wúrà ṣe Ìwọ̀n ojúlówó wúrà ti ó tó talẹ́ǹtì kan ni a gbọdọ̀ fi se ọ̀pá fìtílà àti àwọn ti ó so mọ́ ọn Rí i pé ó ṣe gẹ́gẹ́ bí bátànì ti mo fihàn ọ́ ni orí òkè Àgọ́ Náà Ṣe àgọ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá, aṣọ ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ àti àsọ aláró, ti elésèé àlùkò, àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ni kí ó ṣe iṣẹ́ ọlọ́nà sí wọn Gbogbo aṣọ títa náà ni kí ó jẹ́ déédé ìgbọ̀nwọ́ mèjídínlọ́gbọ̀n ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ni fífẹ̀ Asọ títa márùn ún ni kí o papọ̀ mọ́ ara wọn, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú márùn-ún tókù Ìwọ yóò siṣe ojábó aṣọ aláró sí aṣọ títọ́ kan láti ìsẹ́tí rẹ̀ wá nibi ìsopọ̀, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìwọ yóò ṣe ni etí ìkangun aṣọ títa kejì, ni ibi ìsopọ̀ kejì Ṣe àádọ́ta ọ̀jábó sí aṣọ títa kan, àádọ́ta ojábó ni kí ó ṣe sí etí aṣọ títa ni ìbò mìíràn, pẹ̀lú ọ̀jábó ní ọ̀kánkán ara wọn Nígbà náà ṣe àádọ́ta ìkọ́ yóòkù kí o sì lò wọ́n láti fi fa àwọn aṣọ títa náà papọ̀, nítorí náà àgọ́ náà yóò jẹ́ ọ̀kan Ṣe aṣọ títa irun ewúrẹ́ láti fi ṣe ibò sórí àgọ́ náà—kí ó jẹ́ mọ́kànlá papọ̀ Gbogbo aṣọ títa mọ̀kánlà náà gbọdọ̀ jẹ́ déédé-ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀wọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀ Aṣọ títa márùn ún ni kí ó papọ̀ mọ́ ara wọn sí apá kan àti mẹ́fà tókù sí apá ọ̀tọ̀ Yí aṣọ títa kẹfà po sí méjì níwájú àgọ́ náà Ṣe àádọ́ta ọ̀jábó sí etí òpin aṣọ títa ni apá kan, kí o sì tún ṣe é sí etí òpin aṣọ títa sí apá kejì Nígbà náà ṣe àádọ́ta ìkọ́ idẹ kí o sì kó wọn sínú ọ̀jábó láti fi ṣo àgọ́ náà pọ̀ kí ó lè jẹ́ ọ̀kan Àti ìyóòkù tí ó kù nínú aṣọ títa àgọ́ náà, ìdajì aṣọ títa tí ó kù, yóò rọ̀ sórí ẹ̀yìn àgọ́ náà Asọ títa àgọ́ náà yóò jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan gígùn ní ìhà méjèèjì Èyí tí ó kù yóò rọ̀ sórí ìhà àgọ́ náà láti fi bò ó Ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a ṣe ní pupa fún àgọ́ náà, kí ó sì se awọ ewúrẹ́ sórí rẹ̀ Ṣe pálọ̀ àgọ́ náà pẹ̀lú igi kasia kí ó dúró dáadáa Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí Ṣe ogún pákó sí ìlà gúsù àgọ́ náà Ṣe ogójì ihà ìtẹ̀bọ̀ fàdákà kí ó lọ sí ìṣàlẹ̀ wọn, méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan ní ìṣàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan Àti ìhà kejì, ni ìhà àríwá àgọ́ náà, ṣe ogún pákó ṣíbẹ̀ àti ogójì ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan Ṣe pákó mẹ́fà sí ni ìhà opin ìwọ̀ òòrùn àgọ́ náà, kí o sì se pákó méjì fún igun ní ìhà ẹ̀yìn Ní igún méjèèjì yìí, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ méjì láti ìdí dé orí rẹ̀, a ó sì so wọ́n pọ̀ sí òrùka kan méjèèjì yóò sì rí bẹ́ẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni pákó mẹ́jọ yóò wà, àti ihò itẹ̀bọ̀ mẹ́rìndínlógún fàdákà yóò wà, méjì ní ìṣàlẹ̀ pákó kọ̀ọ̀kan Bákan náà ṣe ọ̀pá ìdábùú igi kaṣíà márùn ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà, Márùn-ún fún àwọn ìhà kejì, àti márùn-ún fún pákó ni ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìhà ẹ̀yìn àgọ́ náà Ọ̀pá ìdábùú àárin ni agbede-méjì gbọdọ̀ tàn láti òpin dé òpin pákó náà Bo àwọn pákó náà pẹ̀lú wúrà, kí o sì ṣe òrùka wúrà kí ó lè di ọ̀pá ìdábùú mu Kí o sì tún bo ọ̀pá ìdábùú náà pẹ̀lú wúrà Gbé àgọ́ náà ró gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fi hàn ọ́ lórí òkè Ìwọ yóò si ṣe aṣọ ìgélé aláró àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ògbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tíí ṣe ọlọ́nà, pẹ̀lú ti àwọn kérúbu ni kí á ṣe é Ìwọ yóò sì fi rọ̀ sára òpó tí ó di igi kaṣíà mẹ́rin ró tí a fi wúrà bò, tí ó dúró lórí ìhò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin Ṣo aṣọ títa náà sí ìṣàlẹ̀ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí sí ẹ̀gbẹ́ aṣọ títa náà Aṣọ títa náà yóò pínyà ibi mímọ́ kúrò ní ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ Fi ìtẹ́ àánú bo àpótí ẹ̀rí náà ni ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ Gbé tábìlì náà sí ìta aṣọ títa náà sí ìhà gúsù àgọ́ náà, kí o sì gbé ọ̀pá fitílà sí ọ̀kánkán rẹ̀ ní ìhà àríwá Fún ti ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, ìwọ yóò ṣe aṣọ títa aláró, elésèé àlùkò, ti òdódó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe Ṣe ìkọ́ wúrà fún aṣọ títa yìí, kí o sì bò ó pẹ̀lú òpó igi kasíà márùn ún pẹ̀lú wúrà Kí o sì dà ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà márùn ún fún wọn Pẹpẹ Ọrẹ Ẹbọ Ṣíṣun Ìwọ yóò sì kọ pẹpẹ igi kaṣíà kan, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gígùn Kí ìhà rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jẹ́ ìwọ̀n kan, ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní fífẹ̀ Ìwọ yóò sìṣe ìwo orí ìgun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, kí àwọn ìwo náà àti pẹpẹ náà lè ṣe ọ̀kan, ìwọ yóò sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ Ìwọ yóò sìṣe abọ́ ìtẹ́dí rẹ láti máa gba eérú rẹ̀, àti ọkọ̀ rẹ̀, àwokòtò rẹ̀, àti fọ́ọ̀kì ẹran rẹ̀, àti àwo iná rẹ̀, gbogbo ohun èlò rẹ̀ ni ìwọ yóò fi idẹ ṣe Ìwọ yóò sí ṣe ni wẹ́wẹ́, ìṣẹ́ àwọ̀n idẹ, kí o sì ṣe òrùka idẹ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìṣẹ́ àwọ̀n náà Gbé e sí abẹ́ igun pẹpẹ náà, kí ó lè dé ìdajì pẹpẹ náà Ìwọ yóò sí ṣe òpó igi kaṣíà fún pẹpẹ náà, kí o sì bò ó pẹ̀lú idẹ A ó sì bọ àwọn òpó náà ní òrùka, wọn yóò sì wà ní ìhà méjèèjì pẹpẹ nígbà tí a bá rù ú Ìwọ yóò síṣe pẹpẹ náà ni oníhò nínú Ìwọ yóò sí ṣe wọ́n bí èyí tí a fi hàn ọ́ ní orí òkè Ìwọ yóò sí ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà Ní ìhà gúsù gbọ́dọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́, pẹ̀lú ogún òpó àti ogún ihò itẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun òpó àti ogún ihò itẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́talélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá Ní ìhà ìlà oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́talélógun ní fífẹ̀, Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta, Àti aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dógún ní gíga yóò wá ní ìhà kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta Àti fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, pèṣè aṣọ títa, mítà mẹ́sàn-án ní gíga, ti aláró, elésèé àlùkò, ti òdòdó, àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe, pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin Gbogbo òpó ti ó wà ní àyíká àgbàlá náà ni a ó fi fàdákà ṣo pọ̀ àti ìkọ́, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ Àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́rìndìnláàdọ́ta ni gíga àti mítà mẹ́talélógún ní fífẹ̀, pẹ̀lú aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn mítà méjì ní gíga, àti pẹ̀lú ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ Gbogbo irú iṣẹ́ tí ó wà kí ó ṣe, papọ̀ pẹ̀lú gbogbo èèkàn àgọ́ náà àti fún tí àgbàlá náà, kí ó jẹ́ idẹ Ìwọ yóò sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọn kí ó mú òróró ólífì dáradára tí a gún fún ọ wá, fún ìmọ́lẹ̀, kí fìtílà lè máa tàn ṣíbẹ̀ Ní àgọ́ àjọ, lẹ́yìn òde láìsí aṣọ ìsélé tí ó wá níwájú ẹ̀rí náà, Árónì àti òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, ni yóò tọ́jú rẹ̀ lati alẹ́, títí di òwúrọ̀ níwájú Olúwa yóò sì di ìlànà láéláé ni ìrandíran wọn lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Isírẹ́lì Aṣọ Àlùfáà Ìwọ sì mú Árónì arákùnrin rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, mú un kúrò ni àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ Nádáhù, Ábíhù, Élíásárì, àti Ítamárì, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà Ìwọ yóò sì dá aṣọ mímọ́ fún Árónì arákùnrin rẹ, láti fún un ni ọ̀ṣọ́ àti ọlá Ìwọ yóò sì sọ fún gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, àwọn ẹni tí mo fún ní ọgbọ́n, kí wọn kí ó lè dá aṣọ fún Árónì, fún ìyà-sí-mímọ́ rẹ̀, kí ó lè ba à sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà Wọ̀nyí ni àwọn aṣọ tí wọn yóò dá ìgbàyà kan, ẹ̀wù èfòdì, ọ̀já àmùrè kan, ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́nà, fìlà àti aṣọ ìgúnwà Kí wọn kí ó dá àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Árónì arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà Wọn yóò sì lo wúrà, aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ dáradára Wọn yóò sì dá ẹ̀wù èfòdì ti wúrà, tí aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókún wíwẹ́ iṣẹ́ ọlọ́nà Kí ó ni aṣọ èjìká méjì tí a so mọ́ igun rẹ̀ méjèèjì, kí a lè so ó pọ̀ Àti onírúurú ọnà ọ̀já rẹ̀, tí ó wà ni orí rẹ̀, yóò rí bákan náà, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ rẹ̀, tí wúrà, ti aṣọ aláró, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ Ìwọ yóò sì mú òkúta óníkísì méjì, ìwọ yóò sì fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sára wọn Ní ti ìbí wọn, orúkọ àwọn mẹ́fà sára òkúta kan àti orúkọ àwọn mẹ́fà tókù sára òkúta kejì Iṣẹ́ ọnà òkúta fínfín, bí ìfín èdìdì àmì, ni ìwọ yóò fún òkúta méjèèjì gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìwọ yóò sì dè wọ́n sí ojú ìdè wúrà Ìwọ yóò sì so wọ́n pọ̀ mọ́ èjìká èfòdì náà ní òkúta ìràntí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Árónì yóò sì máa ní orúkọ wọn ní wájú Olúwa ní èjìká rẹ̀ méjèèjì fún ìrántí Ìwọ yóò sì ṣe ojú ìdè wúrà Àti okùn ẹ̀wọ̀n méjì ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè kí o sì so ẹ̀wọ̀n náà mọ́ ojú ìdè náà Ìwọ yóò fi iṣẹ́ ọgbọ́n ṣe ìgbàyà fún ìpinu iṣẹ́ ọnà gbẹ́nàgbẹ́nà Ìwọ yóò ṣe é bí ẹ̀wù èfòdì ti wúrà, ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ dáradára Kí ìhà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ se déédé—kí ó jẹ́ ìwọ̀n ṣẹ́ńtímítà méjìlélógún ní gíga àti ìwọ̀n ṣẹ̀ńtímítà méjìlélógun ní fífẹ̀ kí o sì ṣe é ní ìsẹ́po méjì Nígbà náà ni ìwọ yóò de òkúta iyebíye mẹ́rin sára ẹṣẹ̀ rẹ̀ Ní ẹṣẹ̀ àkọ́kọ́ ni kí rúbì, tópásì àti bérílì wà ní ẹṣẹ̀ kejì émérálídì, sáfírù, àti díámóńdì ní ẹṣẹ̀ kẹta, lígúrè, ágátè, àti ámétísítì ní ẹṣẹ̀ kẹrin, bérílù, àti óníkísì àti Jásípérì A ó sì tò wọ́n sí ojú wúrà ní dìde wọn Òkúta méjìlá yóò wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olúkúlùkù èdìdì àmì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan bí ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá Fún ìgbàyà náà, ìwọ yóò se okùn ẹ̀wọ̀n ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè Ìwọ yóò ṣe òrùka wúrà méjì fún un, kí o sì so wọ́n mọ́ igun igbá àyà méjèèjì Ìwọ yóò so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì mọ́ òrùka ní igun ìgbàyà náà, àti eti ẹ̀wọ̀n méje ni kí o so mọ́ ojú ìdè méjèèjì, kí o sì fi sí èjìká ẹ̀wù éfódì náà níwájú Ìwọ yóò ṣe òrùka wúrà méjì, ìwọ yóò sì so wọ́n mọ́ igun méjì igbáàyà kejì ní ìhà inú tí ó ti ẹ̀wù éfódì náà Ìwọ yóò sì se orùkọ wúrà méjì, ìwọ yóò sì fi wọ́n sí èjìká ẹ̀wù ẹ́fó dì méjèèjì ní ìṣẹ̀lẹ̀, sí ìhà iwájú rẹ̀, tí ó kọ́jú sí ìṣẹ̀lú rẹ̀, lókè onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù éfódì náà Wọn yóò sì so òrùka ìgbàyà mọ́ òrùka ẹ̀wù èfòdì pẹ̀lú ọ̀já aláró, pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, kí a má ba à tú ìgbàyà náà kúrò lára ẹ̀wù èfòdì náà Nígbà kúgbà tí Árónì bá wọ ibi mímọ́, òun yóò ru orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo ọ̀kan rẹ̀ ni ìgbàyà ìpinu bí ìrántí nígbà gbogbo níwájú Olúwa Bákan náà ìwọ yóò sì mu Úrímù àti Tímímù sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Árónì nígbàkúgbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú Olúwa Árónì yóò sì máa ru ohun ti a ń fi se ìpinu fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọkàn rẹ̀ nígbàgbogbo níwájú Olúwa Ìwọ yóò sìṣe aṣọ ìgúnwà ẹ̀wù éfódì náà ní kìkì aṣọ aláró, pẹ̀lú ojú ọrùn kí ó wà láàrin rẹ̀ fún orí Kí iṣẹ́ ọ̀nà wà létí rẹ̀ bí ìsẹ́tí yí i ká bí agbádá, kí ó má ba à ya Ṣe pómégánátè ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò àti ti òdòdó yí ìsẹ́ti ọ̀já àmùrè náà ká, pẹ̀lú aago wúrà láàrin wọn Àwọn aago wúrà àti àwọn pómégánátè ni kí ó yí ìsẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká Árónì gbọdọ̀ máa wọ̀ ọ́ nígbà tí o bá ń sisẹ́ A ó sì máa gbọ́ ìró àwọn agogo nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ níwájú Olúwa àti nígbà tí ó bá ń jáde bọ̀, kí ó má ba à kú Ìwọ yóò sì ṣe àwo kìkì wúrà, ìwọ yóò sì fín sára rẹ̀ bí, fífín èdìdì àmì pé Mímọ́ sí Olúwa Ìwọ yóò fi ọ̀já aláró sára rẹ̀ ìwọ yóò sì so ó mọ́ fìlà náà kí ó sì wà níwájú fìlà náà Kí ó wà níwájú orí Árónì, kí ó sì lè máa ru ẹ̀bi tí ó jẹ mọ́ ẹ̀bùn mímọ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti yà sí mímọ́, èyíkéyìí tí ẹ̀bùn wọn lè jẹ́ Yóò máa wà níwájú orí Árónì nígbà gbogbo, kí wọn lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa Ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára hun ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára ṣe fìlà Iwọ yóò sì fi ṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ọ̀já àmùrè Ìwọ yóò sì dá ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ọ̀já àmùrè àti ìgbàrí fún àwọn ọmọ Árónì, láti fún wọn ní ọ̀ṣọ́ àti ọlá Lẹ́yìn tí ìwọ ti fi àwọn aṣọ wọ̀nyí wọ Árónì arákùnrin rẹ, ìwọ yóò sì fi wọ àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlú, ìwọ óta òróró sí wọn ní orí, ìwọ yóò sì ya wọ́n sí mímọ́ Ìwọ yóò sì Sọ wọ́n di mímọ́, kí wọn kí o lè máa se iṣe àlùfáà Ìwọ yóò dá aṣọ àwòtẹ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa fi bo ara wọn, kí ó dé ìbàdí dé itan Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ gbọdọ̀ wọ̀ wọ́n nígbàkugbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ lọ tàbí nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ kí wọn kí ó má ba à dẹ́sẹ̀, wọn a sì kú Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún Árónì àti fún irú ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ Ìyàsímímọ́ Àwọn Àlùfáà Èyí ni ohun tí ìwọ yóò ṣe láti yà wọ́n sí mímọ́, nítorí kí wọn lè máa àti láti máa sìn se àlùfáà fún mi Mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan àti àgbò méjì tí kò ní àbùkù Láti ara ìyẹ̀fun aláìwú dídùn, ṣe àkàrà àti àkàrà tí a pò pẹ̀lú òróró, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláìwú tí a da òróró sí Ìwọ yóò sì kó wọn sínú àpẹ̀rẹ̀ kan, ìwọ yóò sì mú wọn wà nínú apẹ̀rẹ̀ náà—papọ̀ pẹ̀lú akọ màlúù àti àgbò méjì náà Nígbà náà ni ìwò yóò mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, ìwọ yóò sì fi omi wẹ̀ wọ́n Ìwọ yóò sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Árónì, àti aṣọ ìgúnwà éfódì, àti éfódì, àti ìgbàyà, kí ó sì fi onírúurú-ọnà ọ̀já ẹ̀wù èfòdì dìí Ìwọ yóò sì fí fìlà dé e ní orí, ìwọ yóò sì se adé mímọ́ sára fìlà náà Nígbà náà ni ìwọ yóò sì mú òrórò ìtasórí, ìwọ yóò sì yà á sí mímọ́ nípa dída òróró sí i ní orí Ìwọ yóò sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ ìwọ yóò sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n ìwọ yóò sì fi fìlà dé wọn ni orí Nígbà náà fi ọ̀já àmùrè di Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ Iṣẹ́ àlùfáà yóò máa jẹ́ ti wọn ní ìlànà títí ayé Báyìí ni ìwọ yóò sì ya Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ Ìwọ yóò sì mú akọ màlúù wá ṣíwájú àgọ́ àjọ, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì fi ọwọ́ lé wọn ní orí Ìwọ yóò sì pa àwọn akọ màlúù náà níwájú Olúwa ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ Ìwọ yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ìka rẹ tọ́ ọ sára ìwo pẹpẹ náà, kí o sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ náà Kí o mú gbogbo ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀ àti ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ Ṣùgbọ́n fi iná sun ẹran akọ màlúù, awọ rẹ̀ àti ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn òde Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Ìwọ yóò sì mú àgbò kan, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò wọ́n-ọn sí pẹpẹ ni gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ Ìwọ yóò sì gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ìwọ yóò sì fọ inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tò wọ́n pẹ̀lú orí rẹ̀ lé ara wọn Nígbà náà ni ìwọ yóò sun àgbò náà lórí pẹpẹ Ẹbọ sísun ni sí Olúwa , olóòórùn dídùn ni, ẹbọ ti a fi iná se sí Olúwa ni Ìwọ yóò mú àgbò kejì, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn Ìwọ yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sí pẹpẹ lórí àti ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ Ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ àti nínú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì wọ́n-ọn sára Árónì àti sára aṣọ rẹ̀, sára àwọn ọmọ rẹ àti sára aṣọ wọn Nígbà náà ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn yóò di mímọ́ Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, iwe méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún Láti inú apẹ̀rẹ̀ ìṣù àkàrà aláìwú, èyí tí ó wà níwájú Olúwa , mú ìṣù kan, àkàrà tí a fi òróró dín àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan Ìwọ yóò fi gbogbo rẹ̀ lé Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa Nígbà náà ni ìwọ yóò sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹ̀lú ẹbọ sísun fún òórùn dídùn níwájú Olúwa , ẹbọ ti a fi iná sun sí Olúwa Ìwọ yóò sì mú igẹ̀ àgbò ìyàsímímọ́ Árónì, ìwọ yóò si fín-in ni ẹbọ fínfín níwájú Olúwa ìpín tìrẹ ni èyí Ìwọ yóò sì yà igẹ̀ ẹbọ fínfìn náà sí mímọ́, àti ìtan ẹbọ àgbésọ-sókè, tí pa fi tí a sì gbésọ-sókè nínú àgbò ìyàsímímọ̀ náà, àní nínú èyí tíí ṣe Árónì àti nínú èyí tí ì ṣe tí àwọn ọmọ rẹ̀ Èyí ni yóò sì máa se ìpín ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà gbogbo Nítorí ẹbọ à-gbé-sọ-sókè ni ẹbọ tí yóò sìṣe èyí ni ẹbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò máa se sí Olúwa láti inú ẹbọ àlàáfíà wọn Asọ mímọ́ Árónì yóò jẹ́ ti irú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí kí a lè máa fi òróró yàn wọ́n kí a sì lè máa yà wọ́n sì mímọ́ Ọmọ rẹ̀ tí ó bá jẹ àlùfáà ní ipò rẹ̀, tí ó bá wọ̀ yóò máa sì wá sí àgọ́ àjọ láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, yóò sì máa wọ̀ wọ́n ní ọjọ́ méje Ìwọ yóò sì mú àgbò fún ìyàsímímọ́, ìwọ yóò sì bọ ẹran wá ní ibi mímọ́ kan Ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ ni Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò ti jẹ ẹran àgbò náà àti àkàrà náà tí ó wà nínú apẹ̀rẹ̀ Wọn yóò sì jẹ nǹkan wọ̀nyí èyí tí a fi se ètùtù náà fún ìyàsímímọ́ àti ìsọdimímọ́ wọn Ṣùgbọ́n kò ní sí ẹlòmíràn ti yóò le è jẹ wọ́n, nítorí pé mímọ́ ni Bí ohun kan nínú ẹran àgbò ìyàsímímọ́ tàbí nínú àkàrà náà bá kù di òwúrọ̀, nígbà náà ni kí ìwọ fi iná sun wọn A kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, nítorí mímọ́ ni Bàyìí ni ìwọ yóò sìṣe fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ bí ohun gbogbo ti mo paláṣẹ fún ọ, ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi yà wọ́n sí mímọ́ Ìwọ yóò sì máa pa akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ní ojoojúmọ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù Ìwọ yóò sì wẹ pẹpẹ mọ́ nípa ṣíṣe ètùtù fún-un, ìwọ yóò sì ta òróró sí i láti sọ ọ́ dí mímọ́ Ní ọjọ́ méje ni ìwọ yóò ṣe ètùtù sí pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì sọ ọ́ di mímọ́ Nígbà náà ni pẹpẹ náà yóò jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohúnkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn-án yóò jẹ́ mímọ́ Èyí ni ìwọ yóò máa fi rúbọ ní orí pẹpẹ náà Òdọ́ àgùntàn méjì ọlọ́dún kan ni ojoojúmọ́ láéláé Odọ àgùntàn kan ni ìwọ yóò fi rúbọ ní òwúrọ̀ àti ọ̀dọ́ Àgùntàn èkejì ní àṣálẹ̀ Pẹ̀lú ọ̀dọ́ àgùntàn ti àkọ́kọ́ rúbọ ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n fulawa dídára tí a fi ìdámẹ́rin hínì òróró lára ólífì tí a gún, àti ìdámẹ́rin hínì wáìnì bí ẹbọ mímu Ọ̀dọ́ àgùntàn kejì ni kí ìwọ ki o pa rúbọ ní àṣálẹ̀ ìwọ yóò sì ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu bí ti òwúrọ̀ fún òórun dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe ni sí Olúwa Fún ìrandíran tó ń bọ̀, ni ẹ ó máa ṣe ẹbọ sísun nígbà gbogbo ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ níwájú Olúwa Níbẹ̀ èmi yóò pàdé yín, èmi yóò sì bá a yín sọ̀rò níbẹ̀ sì tún ni èmi yóò pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a ó sì fi ògo mi ya àgọ́ náà sí mímọ́ Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ya àgọ́ àjọ náà sí mímọ́ àti pẹpẹ náà, èmi yóò sì ya Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ bí àlùfáà fún mi Nígbà náà ni èmi yóò máa gbé láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èmi yóò sì máa ṣe Ọlọ́run wọn Wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, nítorí kí èmi lè máa gbé àárin wọn Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn Mósè àti Igbó Ti Ń Jó Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mósè ń sọ́ agbo ẹran Jẹ́tírò baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Mídíánì Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jínjìn nínú ihà Ó dé Hórébù, òkè Ọlọ́run Níbẹ̀ ni ańgẹ́lì Olúwa ti yọ sí i nínú ọ̀wọ́ iná ti ń jó láàrin igbó Mósè rí i pé iná ń jó nínú igbó ṣùgbọ́n igbó kò run Nígbà náà ni Mósè sọ pé, Èmi yóò lọ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná kò fi jó igbó run Nígbà tí Olúwa rí i pe Mósè ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárin igbó náà, Mósè! Mósè!! Mósè sì dáhùn ó wí pé, Èmi nì yìí Ọlọ́run sì wí fún Mósè pé, Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni Nígbà náà ní ó wí pé, Èmi ni Ọlọ́run baba yín, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù Nítorí ìdí èyí, Mósè fi ojú rẹ̀ pamọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti wo ojú Ọlọ́run Ọlọ́run si wí pé, Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Éjíbítì, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin ibùgbé àwọn ará Kénánì, Hétì, Ámórì, Pérésì, Hífì àti Jébúsì Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, wò ó, igbe àwọn ará Ísírẹ́lì ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Éjíbítì ti se ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà Ǹjẹ́ nísinsínyìí, lọ, Èmi yóò rán ọ sí Fáráò láti kó àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì Ṣùgbọ́n Mósè wí fún Ọlọ́run pé, Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Fáráò lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Mósè pé, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún ọ, tí yóò fihàn pé Èmi ni ó rán ọ lọ Nígbà tí ìwọ bá kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ẹ̀yin yóò sin Ọlọ́run ni orí òkè yìí Mósè sì wí fún Ọlọ́run pé, Bí mo bá tọ̀ àwọn ará Ísírẹ́lì lọ ti mo sì sọ fún wọn pé, Ọlọ́run àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín, tí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ mi pé, Kí ni orúkọ rẹ̀ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn ní ìgbà náà Ọlọ́run sì sọ fún Mósè pé, ÈMI NI TI Ń JẸ́ ÈMI NI Èyí ni ìwọ yóò sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì ÈMI NI ni ó rán mi sí i yín   Ọlọ́run sì tún sọ fún Mósè pé, Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù ti rán mi sí i yín Èyí ni orúkọ mi títí ayérayé, orúkọ ti ẹ ó fi máa rántí mi láti ìran dé ìran Lọ, kó àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, kí o sí sọ fún wọn, Olúwa Ọlọ́run Jákọ́bù yọ sí mi, ó sì wí pé Lóòótọ́ èmi ti ń bojúwò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Íjíbítì Èmi sì ti ṣe ìlérí láti mú un yín jáde kúrò nínú ìpọ́njú yín ni ilẹ̀ Éjíbítì wá sí ilẹ̀ Kénánì, Hítì, Ámórì, Pérésì, Hífì àti Jébúsì ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti oyin Àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì yóò fetí sílẹ̀ sí ohùn rẹ Nígbà náà ni ìwọ, àti àwọn àgbààgbà yóò jọ tọ ọba Éjíbítì lọ, ẹ ó sì wí fún un pé, Olúwa , Ọlọ́run àwọn ará Hébérù ti pàdé wa Jẹ́ kí a lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú ihà láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ọba Éjíbítì kò ní jẹ́ kí ẹ lọ bí kò ṣe pé ọwọ́ ńlá Ọlọ́run wà ni ara rẹ̀ Nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mí láti lu àwọn ará Éjíbítì pẹ̀lú gbogbo ohun ìyanu tí èmi yóò ṣe ni àárin wọn Lẹ́yìn náà, òun yóò jẹ́ kí ẹ máa lọ Èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ bá ojúrere àwọn ará Éjíbítì pàdé Tí yóò fi jẹ́ pé ti ẹ̀yin bá ń lọ, ẹ kò ní lọ ní ọwọ́ òfo Gbogbo àwọn obìnrin ni ó ní láti béèrè lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wọn àti gbogbo àwọn obìnrin ti ń gbé nínú ilé rẹ fún ohun Sílífà àti wúrà àti fún aṣọ, èyí ti ẹ̀yin yóò wọ̀ sí ọrùn àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin Báyìí ni ẹ̀yin yóò sì kó ẹrù àwọn ará Éjíbítì Pẹpẹ Tùràrí Ìwọ yóò sì ṣe pẹpẹ igi kaṣíà kan máa jó tùràrí lórí rẹ̀ Kí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé, kí ó jẹ́ ìdajì mítà ní gígùn, ìdajì mítà ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga rẹ̀—kí ìwo rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀ Ìwọ yóò sì bo òkè rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀ pẹ̀lú u kìkì wúrà, ìwọ yóò sì se wúrà gbà á yíká Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì fún pẹpẹ náà níṣàlẹ̀ ìgbátí méjèèjì ní ọ̀kánkán ìhà rẹ̀—láti gbá àwọn òpó rẹ̀ mú, láti lè máa fí gbé e Ìwọ yóò sì ṣe òpó igi kaṣíà, ìwọ yóò sì bọ́ wọ́n pẹ̀lú wúrà Ìwọ yóò gbé pẹpẹ náà sí iwájú aṣọ títa, èyí tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí níwájú ìtẹ́ àánú èyí tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí níbi ti èmi yóò ti máa bá ọ pàdé Árónì yóò sì máa jó tùràrí dídùn lórí pẹpẹ náà ní àràárọ̀, nígbà tí ó tún àwọn fítìlá náà ṣe Òun yóò sì tún jó tùràrí nígbà tí ó bá tan fìtílà ní àṣálẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní tùràrí yóò máa jó títí láé níwájú Olúwa fún àwọn ìran tó ni ń bọ̀ Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mú Àjèjì tùràrí wá sórí pẹpẹ yìí tàbí ẹbọ sísun kankan tàbí ọrẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ da ẹbọ ohun mímu sórí rẹ̀ Árónì yóò sì máa ṣe ètùtù sórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún Óun yóò sì máa ṣe ètùtù ọdọọdún yìí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ètùtù fún ìran tó ń bọ̀ Mímọ́ jùlọ ni sí Olúwa Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mósè pé, Nígbà tí ìwọ bá ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti mọ iye wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọdọ̀ mú ìràpadà ọkàn rẹ̀ wá fún Olúwa ní ìgbà tí o bá ka iye wọn Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-àrùn kì yóò sún mọ́ wọn, nígbà tí o bá ń ka iye wọn Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì sékéli , gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gérà Ìdajì sékélì yìí ní ọrẹ fún Olúwa Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá sínú àwọn tí a kà láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni yóò fi ọrẹ fún Olúwa Àwọn olówó kì yóò san ju ìdajì sékélì lọ, àwọn talákà kò sì gbọdọ̀ dín ní ìdajì sékélì nígbà tí ẹ̀yin bá mú ọrẹ wá fún Olúwa láti se ètùtù fún ọkàn yín Ìwọ yóò sì gba owó ètùtù náà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìwọ yóò sì fi lé lẹ̀ fún ìsìn àgọ́ àjọ Yóò jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níwájú Olúwa , láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mósè pé, Ìwọ yóò si ṣe agbada idẹ kan, àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ idẹ, fún wíwẹ̀ Ìwọ yóò sì gbé e sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì pọn omi sínú rẹ̀ Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wẹ ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn pẹ̀lú omi tí ó wà nínú rẹ̀ Nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ, wọ́n yóò wẹ̀ pẹ̀lú omi nítorí kí wọ́n má ba à kú Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá sún mọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe ìṣìn, láti mú ẹbọ ti a fi iná sun wá fún Olúwa , wọn yóò sì wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, nítorí kí wọn máa ba à kú Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún Árónì àti irú àwọn ọmọ rẹ̀ fún ìrandìran wọn Olúwa sọ fún Mósè pé, Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta sékélì tí òjíá sísàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́tàlérúgba sékélì tí kínámónì dídùn, àti kane dídùn àádọ́tàlérúgba sékélì, kaṣia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta sékélì-gbogbo rẹ̀ ní ìlànà sékélì ibi mímọ́ àti hínì òrórò ólífì kan Ṣe ìwọ̀nyí ní òróró mímọ́ ìkunra, tí a pò pọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣe-òórùn dídùn tì í ṣe, Yóò jẹ òróró mímọ́ ìtasórí Ìwọ yóò sì lò ó láti ya àgọ́ sí mímọ́ àti àpótí ẹ̀rí náà, tábìlì àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà àti ohun èlò rẹ̀, àti pẹpẹ tùràrí, pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀ Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fí ọwọ́ kàn wọn yóò di mímọ́ Ìwọ yóò sì ta òróró sí orí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè sìn mí bí àlùfáà Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, Èyí ni yóò ṣe òróró mímọ́ ìtasórí mi fún ìrandíran tó ń bọ̀ Má se dà á sí ara ènìyàn kí o má sì ṣe ṣe òróró kankan ni irú rẹ̀ Mímọ́ ni, ẹ̀yín sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára ẹnìkankan yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀   Olúwa sọ fún Mósè pé, Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, óníkà, àti gálíbánúmù àti kìkì tùràrí dáradára, iye kan ni gbogbo rẹ, ṣe tùràrí olóòórùn dídùn tí a pò, iṣẹ́ àwọn olóòórùn, tí ó ní iyọ̀, ó dára, ó sì jẹ́ mímọ́ Ìwọ yóò sì lọ díẹ̀ nínú rẹ̀ kúnná, ìwọ yóò sì gbé e ṣíwájú ẹ̀rí ní àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti pàdé yín Yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ fún yín Ẹ má ṣe se tùràrí kankan ní irú èyí fún'ra yín ẹ kà á ní mímọ́ sí Olúwa Ẹnikẹ́ni tí ó bá se irú rẹ̀ láti máa gbádùn òórùn rẹ̀, òun ni a ó gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ Bésálélì àti Óhólíábù Olúwa wí fún Mósè pé, Wò ó, èmi ti yan Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrì, ti ẹ̀yà Júdà, Èmi sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún-un pẹ̀lú ọgbọ́n, agbára àti ìmọ̀ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà Láti se aláràbarà iṣẹ́ ní wúrà, fàdákà àti idẹ, láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà Ṣíwájú sí i, èmi ti yan Óhólíábù ọmọ Áhúsámákì, ti ẹ̀yà Dánì, láti ràn án lọ́wọ́ Bákan náà, èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́ ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo paṣẹ fún ọ Àgọ́ àjọ náà, àpótí ẹ̀rín pẹ̀lú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò àgọ́ náà, tábìlì àti ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí ó jẹ́ kìkì wúrà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, pẹpẹ tùràrí, pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀ àti aṣọ híhun pẹ̀lú, papọ̀ pẹ̀lú aṣọ mímọ́ fún Árónì àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ bí àlùfáà, òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́ Kí wọ́n se wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe paṣẹ fún ọ Olúwa wí fún Mósè pé, Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, Ẹ̀yín gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́ Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrin èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa , ẹni tí ó yà yín sí mímọ́  Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a óò pa ẹnikẹ́ni tí ó bá se iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a óò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún Olúwa Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ Nítorí náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò se máa pa ọjọ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíràn tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mu títí láé Yóò jẹ́ àmí láàrin èmi àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi   Nígbà tí Olúwa parí ọ̀rọ̀ ṣíṣọ fún Mósè lórí òkè Ṣínáì, ó fún-un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, okuta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Mósè pẹ́ kí ó tó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, wọn péjọ yí Árónì ká, wọ́n sì wí pé, Wá, dá òrìṣà tí yóò máa ṣáájú wa fún wa Bí ó ṣe ti Mósè tí ó mú wa jáde láti Éjíbítì wá, àwa kò mọ́ ohun tí ó ti sẹlẹ̀ sí i Árónì dá wọn lóhùn pé, Ẹ bọ́ òrùka wúrà tí ó wà ní etí àwọn ìyàwò yín, tí àwọn ọmọkùnrin yín, àti tí àwọn ọmọbìnrin yín, kí ẹ sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ènìyàn bọ́ òrùka etí wọn, wọn sì kó wọn wá fún Árónì Ó sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ó sì fi ṣe ohun ọnà fínfin, ó sì dàá ní àwòrán ẹgbọrọ màlúù Nígbà náà ni wọn wí pé, Ísírẹ́lì, wọ̀nyí ni òrìṣà, ti ó mú un yín jáde wá láti Éjíbítì Nígbà ti Árónì rí èyí, ó kọ́ pẹpẹ kan níwájú ẹgbọrọ màlúù náà, ó sì kéde pé, Lọ́la ni àjọyọ̀ sí Olúwa Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n sì rúbọ síṣun, wọ́n sì mú ẹbọ àlàáfíà wá Lẹ́yìn náà wọ́n jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣeré Olúwa sì wí fún Mósè pé, Ṣọ̀kalẹ̀ lọ, nítorí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú gòkè wá láti Éjíbítì, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ Wọ́n ti yára láti yípadà kúrò nínú ohun ti mo pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì ti dá ère ẹ̀gbọrọ màlúù fún ara wọn Wọ́n ti foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì ti rúbọ sí i, wọ́n sì ti sọ pé, Ísíirẹ́lì wọ̀nyí ní òrìṣà tí ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá   Olúwa wí fún Mósè pé, Èmi ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn Ǹjẹ́ nísinsin yìí fi mí sílẹ̀, nítorí kí ìbínú mi lè gbòná sí wọn, kí èmi sì lè pa wọ́n run Nígbà náà ni èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá Ṣùgbọ́n Mósè kígbe fún ojú rere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó wí pé, Olúwa , è é ṣe tí ìbínú rẹ yóò ṣe gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú jáde láti Éjíbítì wá pẹ̀lú agbára ńlá àti ọwọ́ agbára È é ṣe tí àwọn ará Éjíbítì yóò ṣe wí pé, Nítorí ibi ni ó ṣe mọ̀ ọ́ mọ̀ mú wọn jáde, láti pa wọ́n ní orí òkè àti láti gbá wọn kúrò lórí ayé Yípadà kúrò nínú ìbínú rẹ tí ó múná, yí ọkàn padà, kí o má sì ṣe mú ìparun wá sórí àwọn ènìyàn rẹ Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Ábúráhámù, Ísáákì àti Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ búra fún fúnraàrẹ tí o wí fún wọn pé, èmi yóò mú irú ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fún irú ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé   Nígbà náà ni Olúwa yí ọkàn padà, kò sì mú ìparun náà tí ó sọ wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ Mósè sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú okuta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀ Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin Iṣẹ́ Ọlọ́run sì ni wàláà náà ìkọ̀wé náà jẹ́ ìkọ̀wé Ọlọ́run, a fín-in sára àwọn òkúta wàláà náà Nígbà tí Jóṣúà gbọ́ ariwo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kígbe, ó sọ fún Mósè pé, Ariwo ogun wà nínú àgọ́ Mósè dáhùn pé Kì í ṣe ariwo fún ìṣẹ́gun, kì í ṣe ariwo fún aṣẹ́gun ohùn àwọn tí ń kọrin ni mo gbọ́ Nígbà tí Mósè dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì ju pálí ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́ẹ́wẹ́ ní ìṣàlẹ̀ òkè náà Ó sì gbé ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó sì fi iná jó wọn ó sì lọ̀ wọ́n kúnná, ó dà á sínú omi, ó sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mu ún, Mósè sọ fún Árónì pé, Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí Árónì dáhùn wí pé, Má ṣe bínú Olúwa mi Ìwọ mọ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe burú tó Wọ́n sọ fún mi pé, Ṣe òrìsà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa Bí ó ṣe ti Mósè ẹni tí ó mú wa jáde láti Éjíbítì wá àwa kò mọ ohun tí ó sẹlẹ̀ sí i Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún wọn pé, Ẹnikẹ́ni tí ó ní òrùka wúrà, kí ó bọ́ ọ wá Nígbà náà ni wọ́n fún mi ní wúrà, mo sì jù ú sínú iná, a sì fi ṣe ẹgbọrọ màlúù yìí! Mósè rí i pé àwọn ènìyàn náà kòṣe e ṣàkóso àti pé Árónì ti sọ wọ́n di aláìlákóṣo láàrin àwọn ọ̀ta tí ó dìde sí wọn Bẹ́ẹ̀ ni ó dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún Olúwa , kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi Gbogbo àwọn ará Léfì sì péjọ yí i ká Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé, Èyí ni Olúwa , Ọlọ́run Isirẹ́lì, wí pé Kí olúkúlùkù ọkùnrin kí ó kọ idà rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ Ẹ lọ padà, kí ẹ jà láti àgọ́ kan dé òmíràn, olúkúlùkù kí ó pa arákùnrin rẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti aládúgbò rẹ   Àwọn ará Léfì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè ṣe pàṣẹ, àti ní ọjọ́ náà àwọn tí ó kù tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún ènìyàn Nígbà náà ni Mósè wí pé, Ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún Olúwa lónìí, nítorí ìwọ ti dìde sí àwọn ọmọ rẹ àti arákùnrin rẹ, ó sì ti bùkún fún ọ lónìí Ní ọjọ́ kejì Mósè sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, Ẹ̀yin ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi yóò gòkè lọ bá Olúwa bóyá èmi lè se ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni Mósè padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìsà wúrà fún ara wọn Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa oruko mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ Olúwa dá Mósè lóhùn pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi, èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi Ǹjẹ́ nísinsin yìí lọ, máa darí àwọn ènìyàn yìí lọ sí ibi ti mo sọ, angẹ́lì mi yóò sì máa lọ ṣáájú yín Ìgbà ń bọ̀ fún mi tì èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò, èmi yóò fi yà jẹ wọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn Olúwa sì yọ àwọn ènìyàn náà lẹ́nu, pẹ̀lú arun nítorí ohun tí wọ́n se ni ti ẹgbọrọ màlúù tí Árónì ṣe Àgọ́ Àjọ Olúwa sọ fún Mósè pé, Fi ìhín yìí sílẹ̀, ìwọ àti àwọn ènìyàn tí o mú gòkè láti Éjíbítì wá, kí ẹ sì gòkè lọ sí ilẹ̀ tí èmi ti pinnu ní ìbúra fún Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù wí pé, Èmi yóò fi fún irú ọmọ rẹ Èmi yóò rán ańgẹ́lì ṣáájú yín, èmi yóò sì lé àwọn Kénánì, àwọn ará Ámórì, àwọn ará Hítì, àwọn ará Pérísì, àwọn ará Hífì àti àwọn ará Jébúsì jáde Ẹ gòkè lọ sí ilẹ̀ tó ń sán fún wàrà àti oyin Ṣùgbọ́n èmi kò ní lọ pẹ̀lú yín, nítorí ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ̀yin, kí èmi má ba à run yín ní ọ̀nà Nígbà tí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ọ̀rọ̀ ìparun wọ̀nyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì ní kùn, ẹnìkankan kò sì le è wọ ohun ọ̀sọ́ rẹ̀ Nítorí Olúwa ti wí fún Mósè pé, Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, Ènìyàn ọlọ́rùn líle ní ẹ̀yin, bí èmi bá lè wa sí àárin yín ni ìsẹ́jú kan, èmi lè pa yín run Ní sinsin yìí, bọ́ ohun ọ̀sọ́ rẹ kúrò, èmi yóò sì gbèrò ohun tí èmi yóò se pẹ̀lú rẹ   Bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò lára wọn ní òkè Hórébù Mósè máa ń gbé àgọ́ náà, ó sì pa á sí ìta ibùdó, ó jìnnà díẹ̀ sí ibùdó, ó pè é ni Àgọ́ àjọ Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bèrè Olúwa yóò lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà ní ìta ibùdó Nígbàkúgbà tí Mósè bá jáde lọ sí ibi àgọ́, gbogbo ènìyàn á dìde, wọ́n á sì dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn, wọn yóò máa wo Mósè títí yóò fi wọ inú àgọ́ náà Bí Mósè ṣe wọ inú àgọ́ náà, ọ̀wọ̀n àwọ̀ọsánmọ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì dúró sí ẹnu ọnà, nígbà tí Olúwa ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mósè Nígbàkígbà tí àwọn ènìyàn bá rí i ti ọ̀wọ́n àwọ̀ọsánmọ̀ bá dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, gbogbo wọn yóò dìde wọn yóò sì sìn, olúkúlùkù ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀ Olúwa máa ń bá Mósè sọ̀rọ̀ lójúkorojú, gẹ́gẹ́ bí i pé ènìyàn ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ Nígbà náà ni Mósè yóò tún padà lọ sí ibùdó, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin Jósúà ìránṣẹ́ rẹ̀ ọmọ Núnì kò fi àgọ́ sílẹ̀ Mósè sọ fún Olúwa pé, Ìwọ ti ń sọ fún mi, Darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ìwọ kò jẹ́ kí ń mọ ẹni tí ìwọ yóò rán pẹ̀lú mi Ìwọ ti wí pé, Èmi mọ̀ ọ́ nípa orúkọ, ìwọ sì ti rí ojú rere mi pẹ̀lú Bí ìwọ bá ní inú dídùn pẹ̀lú mi, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́, kí n sì le máa wá ojú rere rẹ pẹ̀lú Rántí wí pé orílẹ̀ èdè yìí ènìyàn rẹ ni Olúwa dáhùn wí pé, Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi Nígbà náà ni, Mósè wí fún-un pé, Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má se rán wa gòkè láti ìhín lọ Báwo ni ẹnìkẹ́ni yóò se mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé Olúwa sì sọ fún Mósè pé, Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti bèrè, nítorí inú mi dún sí o, èmi sì mọ̀ ọ́ nípa orúkọ rẹ̀ Mósè sì wí pé Nísinsin yìí fi ògo rẹ hàn mí Olúwa sì wí pé, Èmi yóò sì mú gbogbo ire mí kọjá níwájú rẹ, Èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Olúwa níwájú rẹ Èmi yóò sàánú fún ẹni tí èmi yóò sàánú fún, èmi yóò sì ṣoore-ọ̀fẹ́ fún ẹni tí èmi yóò ṣoore-ọ̀fẹ́ fún Ṣùgbọ́n, ó wí pé, Ìwọ kò le è rí ojú mi, nítorí kò sí ẹnìkan tó rí mi, tí ó lè yè Olúwa sì wí pé, Ibì kan wà lẹ́gbẹ̀ ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, níbi tí o ti lè dúró lórí àpáta Nígbà tí ògo mi bá kọjá, èmi yóò gbé ọ sínú pàlàpálá àpáta, èmi yóò sì bò ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ mi títí èmi yóò fi rékọjá Nígbà tí èmi yóò mú ọwọ́ mi kúrò, ìwọ yóò sì rí ẹ̀yìn mi ṣùgbọ́n ojú mi ni o kò ní rí Òkúta Wàláà Túntún Olúwa sọ fún Mósè pé, E gé òkúta wàláà méjì jáde bí i ti àkọ́kọ́, èmi yóò sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé tó wà lára tí àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fọ́ sára wọn Múra ní òwúrọ̀, kí o sì wá sórí òkè Ṣínáì Kí o fi ara rẹ hàn mí lórí òkè náà Ẹnìkẹ́ni kò gbọdọ̀ wá pẹ̀lú rẹ tàbí kí a rí wọn lórí òkè náà bẹ́ẹ̀ ni agbo àgùntàn tàbí ọwọ́ ẹran kó má ṣe jẹ níwájú òkè náà Bẹ́ẹ̀ Mósè sì gbẹ́ òkúta wàláà méjì bí ti àkọ́kọ́, ó sì gun orí òkè Sínáì lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún-un Ó sì gbé òkúta wàláà méjèèjì náà sí ọwọ́ rẹ̀ Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọ̀ọ̀sánmọ̀, ó sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pòkìkí orúkọ Olúwa Ó sì kọjá níwájú Mósè, ó sì ń ké pé, Olúwa , Olúwa , Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́, Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún , ó sì ń dárí jin àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń sọ̀tẹ̀ àti elẹ́sẹ̀ Ṣíbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ìkẹrin Mósè foríbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ó sì sìn Ó wí pé, Olúwa , bí èmi bá rí ojú rere rẹ, nígbà náà jẹ́ kí Olúwa lọ pẹ̀lú wa Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ènìyàn ọlọ́rùn líle ni wọn, dárí búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ Nígbà náà ni Olúwa wí pé Èmi dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú yín Níwájú gbogbo ènìyàn rẹ èmi yóò se ìyanu, tí a kò tí ì ṣe ní orílẹ̀ èdè ní gbogbo ayé rí Àwọn ènìyàn tí ìwọ ń gbé láàrin wọn yóò rí i bí iṣẹ́ tí èmi Olúwa yóò ṣe fún ọ ti ní ẹ̀rù tó Ṣe ohun tí èmi pa lásẹ fún ọ lónìí Èmi lé àwọn ará Ámórì, àwọn ará Kénánì, àwọn ará Kítì àti àwọn ará Jébúsì jáde níwájú rẹ Má a sọ́ra kí o má ba à bá àwọn ti ó n gbé ilẹ náà tí ìwọ ń lọ dá májẹ̀mú, nítorí wọn yóò jẹ́ ìdíwọ́ láàrin rẹ Wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, fọ́ òkúta mímọ́ wọn, kí o sì gé òpó Ásérè wọn Ẹ má se sin ọlọ́rùn mìíràn, nítorí Olúwa , orúkọ ẹni ti ń jẹ́ òjòwú, Ọlọ́run owú ni Má a sọ́ra kí ẹ má se bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú nígbà tí wọ́n bá ń se àgbérè tọ òrìsà wọn, tí wọ́n sì rúbọ sí wọn, wọn yóò pè yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ ẹbọ wọn Nígbà tí ìwọ bá yàn nínú àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ ní ìyàwó, àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí yóò se àgbérè tọ òrìsà wọn, wọn yóò sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín náà se bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ Ìwọ kò gbọdọ̀ dá ère kankan Àjọ àkàrà àìwú ni kí ìwọ máa pamọ́ Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú, gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa á láṣẹ fún ọ Ṣe èyí ní ìgbà tí a yàn nínú osù Ábíbù, nítorí ní osù náà ni ẹ jáde láti Éjíbítì wá Gbogbo àkọ́bí inú kọ̀ọ̀kan tèmi ní i se, pẹ̀lú àkọ́bí gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ, bóyá ti màlúù tàbí ti àgùntàn Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí ìwọ kí ó fi ọ̀dọ́ àgùntàn rà padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, dá ọrùn rẹ̀ Ra gbogbo àkọ́bí ọkùnrin rẹ padà Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá ṣíwájú mi ní ọwọ́ òfo Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje ìwọ yóò sinmi kó dà ní àkókò ìfúrúgbìn àti ní àkókò ìkórè ìwọ gbọdọ̀ sinmi Ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àkọ́so èso àlìkámà àti àjọ ìkórè ní òpin ọdún Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún, gbogbo àwọn ọkùnrin ni kí ó farahàn níwájú Olúwa , Ọlọ́run Isirẹli Èmi yóò lé orílẹ̀ èdè jáde níwájú rẹ, èmi yóò sì mú kí ìpín rẹ fẹ̀, ẹnikẹ́ni kì yóò gba ilẹ̀ rẹ nígbà tí ìwọ bá gòkè lọ ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún kọ̀ọ̀kan láti farahàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ Má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sí mi pẹ̀lú ohunkóhun tí ó bá ní ìwúkàrà, kí o má sì se jẹ́ kí ẹbọ ìrékọjá kù títí di òwúrọ̀ Mú èyí tí ó dára nínú àkọ́so èso ilẹ̀ rẹ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ Má ṣe ṣe ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀ Olúwa sì wí fún Mósè pé, Kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, nítorí nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni èmi bá ìwọ àti Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú Mósè wà níbẹ̀ pẹ̀lú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru láì jẹ oúnjẹ tàbí mu omi Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà òfin mẹ́wàá sára wàláà Nígbà tí Mósè sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Ṣínáì pẹ̀lú wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀, òun kò mọ̀ pé ojú òun ń dán nítorí ó bá Olúwa sọ̀rọ̀ Nígbà tí Árónì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí Mósè, ojú rẹ̀ ń dán, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti sún mọ́ ọn Ṣùgbọ́n Mósè pè wọn Árónì àti gbogbo àwọn olórí àjọ padà wá bá a, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ Lẹ́yìn èyí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ ọn, ó sì fún wọn ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún-un lórí òkè Ṣínáì Nígbà Mósè parí ọ̀rọ̀ sísọ fún wọn Ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀ Ṣùgbọ́n nígbàkígbà tí ó bá wà níwájú Olúwa láti bá a sọ̀rọ̀, á sí ìbòjú náà títí yóò fi jáde Nígbà tí ó bá sì jáde, á sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ohun tí a ti pa láṣẹ fún-un, wọ́n sì rí i pé ojú rẹ̀ ń dán Mósè á sì tún fi ìbòjú bo ojú rẹ̀ títí á fi lọ bá Olúwa sọ̀rọ̀ Àwọn Ìlànà Ọjọ́ Ìsinmi Mósè pe gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì ó sì wí fún wọn pé, Wọ̀nyí ni àwọn ohun ti Olúwa ti pa láṣẹ fún-un yín láti ṣe Fún ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi ni sí Olúwa Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ni ọjọ́ náà ní a ó pa Ẹ má se dáná kankan ní ibùgbé yín ní ọjọ́ ìsinmi Mósè sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, Èyí ni ohun tí Olúwa pa láṣẹ Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa Ẹnikẹ́ni tí ọ́ bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ aṣọ aláró, elésèé àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára àti irun ewúrẹ́ awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù odò igi kaṣíá òróró ólífì fún títan iná olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn Òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù èfòdì àti igbáàyà Gbogbo ẹni tí ó ní ọgbọ́n láàrin yín, kí ó wa, kí ó sì wá se gbogbo ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ Àgọ́ náà pẹ̀lú àgọ́ rẹ àti ìbòrí rẹ̀, kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ọ̀wọ́n rẹ̀ àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ Àpótí náà pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀, ibò àánú àti aṣọ títa náà tí ó síji bòó Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà Ọ̀pá fìtílà tí ó wà fún títanná pẹ̀lú ohun èlò rẹ̀, fìtílà àti òróró fún títanná Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu ọ̀nà sí Àgọ́ náà Pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú ojú àrò idẹ rẹ̀, òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ agbada idẹ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀ aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú, ọ̀wọ́n àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà Èèkàn àgọ́ náà fún Àgọ́ náà àti fún àgbàlá àti okùn wọn aṣọ híhun láti sisẹ ní ibi mímọ́ aṣọ mímọ́ fún Árónì àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n sìn bí àlùfáà Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kúrò níwájú Mósè, Olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ àti ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbé sókè wá, wọ́n sì mú ọrẹ fún Olúwa , fún isẹ́ Àgọ́ àjọ, fún gbogbo ìsìn rẹ̀ àti fún asọ mímọ́ náà Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ wúrà òrùka etí, òrùka àti ọ̀sọ́ Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún Olúwa Olúkúlùkù ẹni tí ó ni aṣọ aláró elésèé àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára, tàbí irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí a rì ní pupa tàbí awọ màlúù odò, kí ó mú wọn wá Àwọn tí ó mú ọrẹ fàdákà tàbí idẹ wá, mú ọrẹ wá fún Olúwa , àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní igi kasíà fún ipa kankan nínú iṣẹ mú un wá Gbogbo àwọn obìnrin tí ó ní ọgbọ́n ríran owú pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, kí ó mú èyí ti ó ti ran wá ti aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó tàbí ti ọ̀gbọ̀ dáradára Gbogbo àwọn obìnrin tí ó fẹ́, tí ó sì ní ọgbọ́n ń ran òwú irun ewúrẹ́ Àwọn olórí mú òkúta óníkísì wá láti tò ó lórí ẹ̀wù éfódì àti igbáàyà Wọ́n sì tún mú olóòrùn àti òróró ólífì wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn Gbogbo àwọn ènìyàn Isirẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún Olúwa fún gbogbo iṣẹ́ tí Olúwa ti pa láṣẹ fún wọn láti se nípaṣẹ̀ Mósè Nígbà náà ni Mósè wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, Wò ó, Olúwa ti yan Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrì, ti ẹ̀yà Júdà, Ó sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún-un, pẹ̀lú ọgbọ́n, agbára, ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú isẹ́ ọnà Láti má a se aláràbarà iṣẹ́ ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ, láti gbẹ́ òkúta àti láti tò ó, láti fún igi àti láti sísẹ ni gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà Ó sì fún òun àti Óhólíábù ọmọ Áhísámákì ti ẹ̀yà Dánì, ni agbára láti kọ́ àwọn tókù Ó sì fi ọgbọ́n kún wọn láti se gbogbo onírúurú iṣẹ́, ti oníṣọ̀nà, ti ayàwòrán, ti aránsọ, ti alásọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ní ọ̀gbọ̀ dáradára àti ti ahunsọ, gbogbo èyí tí ọ̀gá onísẹ́ ọnà àti ayàwòrán ń ṣe Àgọ́ náà Bésálélì, Óhólíábù àti olúkúlùkù ọlọ́gbọ́n ẹni tí Olúwa tí fún ní ọgbọ́n àti agbára láti mọ bí a ti í ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ ni kí wọn ṣe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ Mósè sì pe Bésálélì àti Óhóábù àti gbogbo ọlọ́gbọ́n ènìyàn ẹni tí Olúwa ti fún ni agbára àti gbogbo ẹni tí ó fẹ́ láti wá sé iṣẹ́ náà Wọ́n gba gbogbo ọrẹ tí àwọn ọmọ Isirẹli ti mú wá lọ́wọ́ Mósè fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà Àwọn ènìyàn sì ń mú ọrẹ àtinúwá wá ní àràárọ̀ Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́ ọnà tí wọn ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀ Mósè sì wí pé, Àwọn ènìyàn mú púpọ̀ wá fún síṣe iṣẹ́ náà ju bi Olúwa ti pa á láṣẹ láti ṣe lọ Mósè sì pàṣẹ, wọ́n sì rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo ibùdó Kí ọkùnrin tàbí obìnrin má ṣe ṣe ohun kankan bí ọrẹ fún ibi mímọ́ náà mọ́ Bẹ́ẹ̀ ni a dá àwọn ènìyàn lẹ́kun láti mú un wá sí i, nítorí ohun tí wọ́n ti ni ti ju ohun tí wọn fẹ́ fi ṣe gbogbo iṣẹ́ náà lọ Gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin láàrin àwọn òṣìṣẹ́ ni wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, tí aṣọ aláró, ti elésèé àlukò àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ṣe iṣẹ́ sí wọn nípa ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà Gbogbo aṣọ títa náà jẹ́ ìwọ̀n kan ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n ní gíga àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀ Wọ́n sì pa aṣọ títa márùn-ún pọ̀ mọ̀ ara wọn, wọ́n sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ sì márùn-ún tó kù Wọ́n sì pa ajábó aṣọ aláró ní etí aṣọ títa kan láti ìsẹ́tí rẹ̀ dé ibi òpin, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní o ṣe sí ìhà etí ikangun aṣọ títa kejì ní ibi òpin èkejì Àádọ́ta ajábó ní ó pa lára aṣọ títa kan, àti àádọ́ta ajábó ni ó sì lò pa ní etí aṣọ títa tí ó wà ní ọ̀kánkán ara wọn Wọ́n sì ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì lò wọ́n láti fi kọ́ méjì aṣọ títa papọ̀ bẹ́ẹ̀ Àgọ́ náà sì di ọ̀kan Wọ́n ṣe aṣọ títa ti irun ewúrẹ́ fún Àgọ́ náà lórí Àgọ́ náà mọ́kànlá ni gbogbo rẹ̀ papọ̀ Gbogbo aṣọ títa mọ́kọ̀ọ̀kànlá náà jẹ́ ìwọ̀n kan ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́, ní gígá àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀ Wọ́n so àsọ títa márùn-ún pọ̀ mọ́ ara wọn, wọ́n sì tún so mẹ́fà tó kù mọ́ ara wọn Wọ́n sì pa àádọ́ta ajábó sí ìsẹ́tí ìkángun aṣọ títa ní apá kan, wọ́n sì tún pa ajábó mìíràn sí ìsẹ́tí ìkángun aṣọ títa ní apá ibòmíràn Wọ́n ṣe àádọ́ta ìkọ́ idẹ láti so Àgọ́ náà pọ̀ kí o lè jẹ́ ọ̀kan Wọ́n sì ṣe ìbòrí àwọ àgbò tí a rì ní pupa, àti ìbòrí màlúù odò lórí rẹ̀ Wọ́n ṣe pákó igi kaṣíá tí ó dúró fún Àgọ́ náà Ọ̀kọ̀ọ̀kan pákó náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀, pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì tí ó kọjú sí ara wọn Wọ́n ṣe gbogbo pákó Àgọ́ náà bí èyí Wọn ṣe ogún pákó sí ìhà gúsù Àgọ́ náà Wọ́n sì ṣe ogójì fàdákà ihò ìtẹ̀bọ̀ lọ sí ìṣàlẹ̀ wọn ìtẹ̀bọ̀ méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìṣàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ Fún ìhà kejì, ìhà àríwá Àgọ́ náà, wọ́n ṣe ogún pákó ogójì fàdákà ihò ìtẹ̀bọ̀ méjì ní ìṣàlẹ̀ pákó kọ̀ọ̀kan Wọ́n ṣe pákó mẹ́fà sì ìkángun, ní ìkangun ìhà ìwọ̀ oòrùn Àgọ́ náà, pákó méjì ni wọ́n ṣe sí igun Àgọ́ náà ní ìkangun Ní igun méjèèjì yìí, pákó méjì ni ó wà níbẹ láti ìdí dé orí rẹ̀ wọ́n sì kó wọ́n sí òrùka kan méjèèjì rí bákan náà Wọ́n jẹ́ pákó mẹ́jọ àti fàdákà mẹ́rìn-lélógún ìhò ìtẹ̀bọ̀, méjì wà ní ìṣàlẹ̀ kọ̀ọ̀kan Wọ́n sì tún ṣe ọ̀pá igi kaṣíà márùn ún fún pakó ní ìhà kọ̀ọ̀kan Àgọ́ náà, márùn-ún fún àwọn tí ó wà ní ìhà kejì, márùn-ún fún pákó tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìkangun Àgọ́ náà Wọ́n sì ṣe ọ̀pá àárin tí yóò fi jáde láti ìkangun dé ìkangun ní àárin àwọn pákó náà Wọ́n bo àwọn pákó pẹ̀lú wúrà, wọ́n sì ṣe àwọn òrùkà wúrà láti gbá ọ̀pá náà mú Wọ́n sì tún bo ọ̀pá náà pẹ̀lú wúrà Wọ́n ṣe aṣọ títa ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, wọ́n ṣe kérúbù si pẹ̀lú ọgbọ́n oníṣẹ́ ọnà Wọ́n sì ṣe òpó igi kasíá mẹ́rin fún-un wọ́n sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà Wọ́n sì ṣe àwọn ìkọ́ wúrà fún wọn, wọ́n sì gba ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rin wọn Fún ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà wọ́n ṣe aṣọ títa ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkù, ti òdòdò àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára iṣẹ́ abẹ́rẹ́ wọ́n sì ṣe òpó márùn-ún pẹ̀lú ìkọ́ wọn Wọ́n bo orí àwọn òpó náà àti ìgbànú wọn pẹ̀lú wúrà, wọn sì ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ márùn-ún wọn ní idẹ Àpótí Náà Bésálélì se àpótí igi kasíá ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀ Ó fi kìkì wúrà bò ó nínú àti lóde, ó sì fi wúrà gbà á léti yíká Ó sì dá òrùka wúrà mẹ́rin fún un, ó so wọ́n mọ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, pẹ̀lú òrùka méjì ní ìhà kìn-ín-ní àti òrùka méjì ni ìhà kejì Ó sì tún ṣe òpó igi kaṣíà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà Ó sì kó àwọn òpó náà sínú òrùka ní ìhà àpótí náà láti máa fi gbé e Ó se ìbòrí àánú kìkì wúrà ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀ Ó sì se kérúbù méjì láti inú òlù wúrà ní òpin ìbòrí náà Ó se kérúbù kan ni òpin èkínní, ó sì tún ṣe kérúbù kejì sí èkejì ní òpin méjèèjì ó ṣe ìtẹ́ àánú ìbòrí wọn Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè sí i, ó fi ìji bo ìbòrí wọn Àwọn kérúbù kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìbòrí náà Ó se tábìlì igi kaṣíá ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga Ó sì fi kìkì wúrà bòó, ó sì se ìgbátí yí i ká Ó sì tún ṣe etí ìbù ọwọ́ fífẹ̀ yìí ká, ó sì fi ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká Ó sì dá òrùka wúrà fún tábìlì náà, ó sì so wọ́n mọ́ igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, níbi tí ẹṣẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wà Àwọn òrùka náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ etí rẹ̀ láti gbá àwọn òpó náà mu láti máa fi gbé tábìlì náà Igi kaṣíá ni ó fi se òpó ti a fi ń gbé tábìlì náà, ó sì fi wúrà bò ó Ó sì ṣe àwọn ohun èlò tí ó wà lórí tábìlì náà ní kìkì wúrà, abọ́ rẹ̀, àwo rẹ, àwokòtò rẹ̀ àti ìgò rẹ̀ fún dída ọrẹ mímu jáde Ó sì se ọ̀pá fìtílà náà ní kìkì wúrà ó sì lù ú jáde, ọ̀pá rẹ̀, ìtànná ìfẹ́ rẹ̀, irudi rẹ àti ago rẹ̀, wọ́n jẹ́ òkan náà Ẹ̀ka mẹ́fà ní ó jáde láti ìhà ọ̀pá fìtílà náà mẹ́ta ní ìhà àkọ́kọ́ àti mẹ́ta ní ìhà èkejì Kọ́ọ̀bù mẹ́ta ni a se bí ìtànná alímóndì pẹ̀lú ìrùdí àti ìtànná wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta sì tún wà ní ẹ̀ka mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni ní ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà jáde lára ọ̀pá fìtílà Lára ọ̀pá fìtílà náà ni a se kọ́ọ̀bù mẹ́rin bí ìtànná alímóndì, ìrùdí rẹ̀ àti ìtànná rẹ̀ Ìrùdí kan níṣàlẹ̀ ẹ̀ka méjì jáde lará ọ̀pá fìtílà náà, ìrùdí kejì níṣàlẹ̀ èkejì, àti ìrùdí kẹ́ta níṣàlẹ̀ ìrùdí ìkẹta-ẹ̀ka mẹ́fà lò wà lára gbogbo rẹ̀ Ìrùdí náà àti ẹ̀ka wọn jẹ́ bákan náà, ó lù ú jáde ní kìkì wúrà Ó se fìtílà méje rẹ̀, pẹ̀lú àlùmágàjí àti àwo rẹ̀ kìkì wúrà ni Ó sì se ọ̀pá fìtílà náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ láti ara talẹ́ńtì kan tí ó jẹ́ kìkì wúrà Igi kaṣíá ní ó fi ṣe pẹpẹ tùràrí náà Igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ jẹ́ déédé, gígùn rẹ̀ jẹ ìdajì mítà, fífẹ̀ rẹ̀ náà jẹ́ ìdajì mítà àti gíga rẹ̀ sì jẹ́ mítà kan-ìwo rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà Kìkì wúrà ni ó fi bo orí rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀, ó sì fi ìgbátí wúrà yìí ká Ó se òrùka wúrà méjì sí ìṣàlẹ̀ ìgbátí náà méjì ní ọ̀kánkán ara wọn láti gbá òpó náà mú láti máa fi gbé e Ó ṣe òpó igi kaṣíá, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú u wúrà Ó sì tún ṣe òróró mímọ́ ìtasórí àti kìkì òórùn dídùn tùràrí-iṣẹ́ àwọn tí ń ṣe nǹkan olóòórùn Pẹpẹ Ẹbọ Sísun Ó sì fi igi kaṣíá kọ́ pẹpẹ ẹbọ sísun, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni gíga rẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún, igun rẹ̀ ṣe déédé Ó ṣe ìwo sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, nítorí kí ìwo àti pẹpẹ náà lè jẹ́ ọ̀kan, ó sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ Idẹ ni ó ṣe gbogbo ohun èlò pẹpẹ, ìkòkò rẹ̀, ọkọ, àwokòtò rẹ̀, fọ́ọ̀kì tí a fi rí mú ẹran àti àwo iná rẹ̀ Ó ṣe àrò fún pẹpẹ náà, àwọ̀n onídẹ, kí ó wà níṣàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, dé ìdajì òkè pẹpẹ náà Ó dá òrùka idẹ láti mú kí ó di òpó igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin idẹ àrò náà mú Ó sì fi igi kasíà ṣe àwọn òpó náà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú idẹ Ó sì fi òpó náà bọ inú òrùka, nítorí kí ó lè wà ní ìhà pẹpẹ náà láti máa fi gbé e Ó sì sé e ní oníhò nínú Ó ṣe agbada idẹ, o sì fi idẹ ṣe ẹṣẹ̀ rẹ̀ ti àwòjíji àwọn obìnrin tí ó ń sìn ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ Ó sì ṣe àgbàlá náà Ní ìhà gúsù ni aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára wà, ó jẹ́ mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta ní gígùn , pẹ̀lú ogún òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, àti pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà Ní ìhà àríwá náà tún jẹ mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta ní gígùn, ó sì ní ogún òpó àti ogun ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà Ìhà ìwọ̀ oòrùn jẹ́ mítà mẹ́talélógún ní fífẹ̀, ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà pọ̀ Fún ìhà ìlà oòrùn, sí ibi tí oòrùn ti ń yọ náà jẹ́ mítà mẹ́talélógún ni fífẹ̀ Aṣọ títa ìhà ẹnu ọ̀nà kan jẹ́ mítà mẹ́fà ààbọ̀, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta, àti aṣọ títa ní ìhà kejì tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ mítà mẹ́fà ààbọ̀ pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́fà Gbogbo aṣọ tí ó yí àgbàlá náà jẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára Ihò ìtẹ̀bọ̀ fún òpó náà idẹ ni Ìkọ́ òpó náà àti ìgbànú tí ó wà lára òpó náà jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà gbogbo àwọn òpó àgbàlá náà ní ìgbànú fàdákà Aṣọ tita fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára iṣẹ́ alábẹ́rẹ́ ni Ó jẹ́ mítà mẹ́sàn-án ní gígùn , gẹ́gẹ́ bí aṣọ títa àgbàlá náà, àti gíga rẹ̀ jẹ mítà méjì , pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ mẹ́rin Ìkọ́ àti ìgbànú wọn jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà Gbogbo èèkàn àgọ́ tabánákù náà àti ti àyíká àgbàlá náà jẹ́ idẹ Wọ̀nyí ni iye ohun èlò tí a lò fún tabánákù náà, tabánákù ẹ̀rí, èyí ti a kọ bí òfin Mósè nípa àwọn ọmọ Léfì ní abẹ́ àkóso Itamari ọmọ Árónì àlùfáà Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ńtì mọ́kàndínlọ́gbọ̀n àti ẹgbẹ̀rin sékélì gẹ́gẹ́ bí i sékélì ibi mímọ́ Sílífà tí a rí nínú ìjọ, ẹni tí a kà nínú ìkànìyàn jẹ́ ọgọ́rùn-ún talẹ́ntì àti òjìlélẹ́gbẹ̀sán ó lé mẹ́ẹ̀dógún sékélì gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́ ìwọ̀n gíráàmù márùn-ún ààbọ̀ lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n-ọ̀kẹ́-lé-ẹgbẹ̀tadínlógún-ó-lé-àádọ́jọ ọkùnrin Ọgọ́run-ún talẹ́ntì fàdákà ní a lò láti fi dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ibi mímọ́ àti fún aṣọ títa ọgọ́rùnún ihò ìtẹ̀bọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún talẹ́ntì náà talẹ́ntì kan fún ihò ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan Ó lo òjìdínlẹ́gbẹ̀san ó lé mẹ́ẹ̀dogun sékélì ìwọ̀n ogún gíráàmù ni ó fi ṣe ìkọ́ fún òpó náà, láti fi bo orí òpó náà àti láti fi ṣe ìgbànú wọn Idẹ ara ọrẹ náà jẹ́ àádọ́rin tálẹ́ntì àti egbèjìlá sékélì Ó lò ó láti fi ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, pẹpẹ idẹ náà pẹ̀lú àrò idẹ rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ihò ìtẹ̀bọ̀ fún àyíká àgbàlá náà àti èyí tí ó wà fún ẹnu ọ̀nà àti gbogbo èèkàn àgọ́ náà fún tabánákù àti èyí tí ó wà fún àyíká àgbàlá náà Asọ Àlùfáà Nínú aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò àti ti òdòdó ni wọ́n fi ṣe aṣọ híhun fún àwọn òsìsẹ́ ní ibi mímọ́ Ó sì tún dá aṣọ mímọ́ fún Árónì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Ó ṣe ẹ̀wù èfòdì wúrà, ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára Ó sì lu wúrà náà di ewé fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì tún gé e láti fi ṣe iṣẹ́ sí aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó, àti sínú ọ̀gbọ̀ dáradára ni ti iṣẹ́ ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà Ó ṣe aṣọ èjìká fún ẹ̀wù èfòdì náà, èyí tí ó so mọ igun rẹ̀ méjèèjì, nítorí kí ó lè so pọ̀ Ọnà ìgbànú híhun rẹ̀ rí bí i ti rẹ̀ ó rí bákan náà pẹ̀lú ẹ̀wù èfòdì ó sì sé e pẹ̀lú wúrà, àti pẹ̀lú aṣọ aláró, elésèé àlùkò, òdòdó àti pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pà sẹ fún Mósè Ó ṣìṣe òkúta óníkísì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ó sì so wọ́n mọ́ asọ èjìká ẹ̀wù èfòdì náà bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Isirẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pà sẹ fún Mósè Ó ṣe iṣẹ́ ọnà sí igbáyà náà iṣẹ́ ọgbọ́n ọlọ́nà Ó ṣe é bí, ẹ̀wù èfòdì ti wúrà ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára Igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé ìwọ̀n ṣẹ̀ǹtímítà méjìlélógún ni gígùn rẹ̀, fífẹ̀ rẹ̀ náà sì jẹ́ ìwọ̀n sẹ̀ǹtímítà méjìlélógún ó sì jẹ́ ìsẹ́po méjì Ó sì to ìpele òkúta mẹ́rin oníyebíye sí i Ní ipele kìn-in-ní ní rúbì wà, tapásì àti bérílù ní ipele kejì, túríkúóṣè, sáfírù àti émérálídì ní ipele kẹta, Jásínítì, ágátè àti amétístì ní ipele kẹ́rin, kárísólítì, oníkísì, àti jásípérì Ó sì tò wọ́n ní ojú ìdè wúrà ní títò wọn Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá ọkan fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnikọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá Fún igbáyà náà, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n iṣẹ́ kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bi okùn Wọ́n sì ṣe ojú ìdè wúrà méjì àti òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so àwọn òkúta náà mọ́ igun méjèèjì igbáàyà náà Wọ́n sì so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì náà mọ́ àwọn òrùkà náà ni igun igbáàyà náà, àti ní àwọn òpin ẹ̀wọ̀n tókù ni wọ́n fi mọ ojú ìdè méjèèjì, wọ́n so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù èfòdì náà ní iwájú Wọ́n ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so wọ́n mọ́ igun méjèèjì igbáyà náà ní etí tí ó wà ní inú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀wù èfòdì náà Wọ́n sì tún ṣe òrùka wúrà méjì sí i, wọ́n sì so wọ́n mọ́ ìdí aṣọ èjìká ní iwájú ẹ̀wù èfòdì náà tí ó sún mọ́ ibi tí a ṣe lọ́sọ̀ọ́ ní òkè ìgbànú ẹ̀wù èfòdí náà Wọn ṣo àwọn òrùka igbáàyà mọ́ àwọn òrùka ẹ̀wù èfòdì ọ̀já aṣọ aláró, kí a pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, nítorí kí igbáàyà náà má ṣe tú kúrò lára ẹ̀wù èfòdì náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Ó sì ṣe ọ̀já àmùrè ẹ̀wù èfòdì gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ aláró iṣẹ́ alásọ híhun Pẹ̀lú ihò ní àárin ọ̀já àmùrè náà gẹ́gẹ́ bí i ojú kọ́là, àti ìgbànú yí ihò yìí ká, nítorí kí ó má ba à ya Ó sì ṣe pomégíránátè ti aṣọ aláró, elésèé àlùkò, òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára yí ìsẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká Ó sì ṣe ago kìkì wúrà, ó sì ṣo wọ́n mọ́ àyìká ìsẹ́tí àárin pomégíránátè náà Aago àti pomégíránátè kọjú sí àyíká ìsẹ́ti ọ̀já àmùrè láti máa wọ̀ ọ́ fún iṣẹ́ àlùfáà, bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ, wọ́n ṣe àwọ̀tẹ́lẹ̀ ti ọ̀gbọ̀ dáradára tí iṣẹ́ alásọ híhun Àti fìlà ọ̀gbọ̀ dáradára, ìgbàrí ọ̀gbọ̀ àti aṣọ abẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára Ọ̀já náà jẹ́ ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti òdòdó iṣẹ́ alábẹ́rẹ́ bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mósè Ó ṣe àwo, adé mímọ́, láti ara kìkì wúrà, wọ́n sì kọ̀wé sí i, gẹ́gẹ́ bí i ìkọ̀wé lórí èdìdì MÍMỌ́ SÍ Olúwa Wọ́n sì so ọ̀já aláró mọ́ ọn láti ṣo ó mọ́ fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ti àgọ́ àjọ parí Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàsẹ fún Mósè Wọ́n sì mú tabánákù náà tọ Mósè wá àgọ́ náà àti gbogbo ohun ọ̀sọ́ rẹ̀, ìkọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, òpó rẹ̀ àti àwọn ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ ìbòrí awọ àgbò tí a kùn ní pupa, ìbòrí awọ àti ìji àsọ títa àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti ìbòrí àánú tábìlì pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà pẹ̀lú ipele fìtílà rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti òróró fún títanná rẹ̀ pẹpẹ wúrà àti òróró ìtasórí, tùràrí dídùn, àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà Pẹpẹ idẹ pẹ̀lú idẹ ọlọ, àwọn òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀ aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti àgbàlá, àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá ọ̀já àmùrè àti èèkàn àgọ́ fún àgbàlá náà gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ fún àgọ́, àgọ́ àjọ náà aṣọ híhun tí wọ́n ń wọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, aṣọ mímọ́ fún Árónì àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ àlùfáà Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣe gbogbo iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti páṣẹ fún Mósè Mósè bẹ iṣẹ́ náà wò, ó sì rí i wí pé wọ́n ti ṣe é gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pà ṣẹ Nítorí náà Mósè sì bùkún fún wọn Àwọn Àmì Fún Mósè Mósè dáhùn ó sì wí pé Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà mí gbọ́ ń kọ́ Tàbí tí wọn kò fi etí sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ́nu mi, tí wọn sì wí pé, Olúwa kò farahàn ọ́ Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún un pé, Kí ni ó wà ní ọwọ́ ọ̀ rẹ nnì Ó sì dáhùn pé, ọ̀pá ni Olúwa sì sọ pé, Sọ ọ̀pá náà sílẹ̀ Mósè sì sọ ọ̀pá náà sílẹ̀, lọ́gán ni ọ̀pá náà di ejò, ó sì sá fún un Nígbà náà ni Ọlọ́run wá sọ fún un pé, na ọwọ́ rẹ, kí o sì mú un ni ìrù Mósè sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mu ejò náà, ejò náà sì padà di ọ̀pá tí ó wà ni ọwọ́ rẹ̀ Olúwa sì wí pé, Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí wọn bá à le è gbàgbọ́ pé, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì, àtì Ọlọ́run Jákọ́bù tí farahàn ọ́ Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, Ti ọwọ́ rẹ bọ ìnú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀ Mósè sì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú aṣọ ní igbá àyá rẹ̀, ní ìgbá ti ó sì yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ ti dẹ́tẹ̀, ó sì ti funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú Ó sì wí pé, Nísinsìnyìí, fi ọwọ́ náà padà sí abẹ́ aṣọ ní igbá àyà rẹ Mósè sì ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ́ sípò bí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ tó kù Ní ìgba náà ni Olúwa wí pé Bí wọn kò bá gbà ọ́ gbọ́ tàbí kọ ibi ara sí iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, wọ́n le è ti ipaṣẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kejì gbàgbọ́ Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gba àwọn méjèèjì wọ̀nyí gbọ́, tí wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ, bu omi díẹ̀ láti inú odò Náílì kí o si dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi tí ìwọ bù láti inú odò yìí yóò sì di ẹ̀jẹ̀ Mósè sì sọ fún Olúwa pé, Èmi jẹ́ akọ́lòlò, èmi kì í ṣe ẹni tó lè sọ̀rọ̀ já gaara láti ìgbà àtijọ wá tàbí láti ìgbà ti o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, mo jẹ́ ẹni ti ahọ́n rẹ̀ lọ́ tí ó sì ń lọ́ra àti sọ̀rọ̀ Olúwa sì sọ fún un pé, Ta ni ó fún ènìyàn ni ẹnu Ta ni ó mú un ya odi tàbí adití Ta ni ó mú un ríran, tàbí mú un fọ́jú Ǹjẹ́ kì í ṣe Èmi Olúwa Lọ nísinsìnyìí, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀ Èmi yóò sì kọ́ ọ ni ohun ti ìwọ yóò sọ Mósè dáhùn ó wí pé, Olúwa jọ̀wọ́ rán ẹlòmíràn láti lọ ṣe iṣẹ́ yìí Ìbínú Ọlọ́run ru sókè sí Mósè, ó sì sọ pé, Árónì ará Léfì arákùnrin rẹ ńkọ́ Mo mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ já gaara, ó ti wà ní ọ̀nà rẹ̀ báyìí láti pàdé e rẹ Inú rẹ̀ yóò sì dùn ti ó bá rí ọ Ìwọ yóò sọ̀rọ̀ fún un, ìwọ yóò sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu Èmi yóò ràn yín lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀ Èmi yóò kọ́ ọ yín ni ohun ti ẹ ó ṣe Òun yóò bá ọ sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn, yóò sì dàbí i pé ẹnu un rẹ ni a gbà sọ ọ̀rọ̀ náà, ìwọ yóò sì dàbí Ọlọ́run ní iwájú rẹ̀ Ṣùgbọ́n mú ọ̀pá yìí ni ọwọ́ rẹ kí ìwọ bá à lè fi ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ìyanu pẹ̀lú rẹ̀ Mósè padà sí ọdọ Jẹ́tírò baba ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ fún un pé, Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n padà tọ àwọn ènìyàn mi lọ ni ilẹ̀ Íjíbítí láti wò bóyá wọ́n sì wà láàyè ṣíbẹ̀ Jẹ́tirò sì dáhùn, ó wí pé, Má a lọ ni àlàáfíà Nísínsìnyìí, Olúwa ti sọ fún Mósè ni ilẹ̀ Mídíánì pé, Má a padà lọ sí Éjíbítì, nítorí àwọn ti ó fẹ́ pa ọ ti kú Mósè mú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó kó wọn lé orí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ padà sí Éjíbítì Ó sì mú ọ̀pa Ọlọ́run sí ọwọ́ rẹ̀ Olúwa sì sọ fún Mósè pé, Ní ìgbà tí ìwọ bá padà sí Éjíbítì rí i pé ìwọ se iṣẹ́ ìyanu ni iwájú Fáráò Èmi ti fún ọ lágbára láti ṣe é Èmi yóò sì ṣé àyà rẹ̀ le, òun kì yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà kí ó lọ Lẹ́yìn náà, kí o sọ fún Fáráò pé, Èyí ni Olúwa sọ Ísírẹ́lì ní àkọ́bí ọmọ mi ọkùnrin, mo sọ fún ọ, Jẹ́ kí ọmọ mi lọ, ki òun kí ó lè máa sìn mí Ṣùgbọ́n ìwọ kọ̀ láti jẹ́ kí ó lọ nítorí náà, èmi yóò pa àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin   Ní ọ̀nà ìrìnàjò rẹ, ni ibi tí wọ́n gbé sùn ní ilé-èrò ní alẹ́, Olúwa pàdé Mósè, ó sì fẹ́ láti pa á Ṣùgbọ́n Ṣípórà mú ọ̀bẹ òkúta mímú, ó sì kọ ọmọ rẹ̀ ní ilà abẹ́, ó si fi awọ rẹ̀ kan ẹṣẹ̀ Mósè Ṣípórà sì wí pé, Ọkọ ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ jẹ́ sí mi Nítorí náà Olúwa yọ̀ǹda rẹ láti ìgbà tí ó ti wí pé, Ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ í ṣe Èyí tó túmọ̀ sí àkọlà abẹ́ Olúwa sì sọ fún Árónì pé, Lọ sínú ihà láti lọ pàdé Mósè Ní ìgbà náà ni ó lọ pàdé Mósè ní orí òkè Ọlọ́run, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu Ní ìgbà náà ni Mósè sì sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti sọ fún un àti nípa gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un láti ṣe ní iwájú Fáráò Mósè àti Árónì pe gbogbo àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ Árónì sọ ohun gbogbo tí Olúwa sọ fún Mósè fún wọn Wọ́n sì gbàgbọ́ Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Olúwa ti bẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wò àti pé Olúwa ti gbọ́ nípa ìpọ́njú wọn, wọ́n tẹríba, wọ́n sì sìn ín Ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ amì náà níwájú àwọn ènìyàn náà Gbígbé Àgọ́ Ró Olúwa sì wí fún Mósè pé Ní ọjọ́ kìn-ín-ní Oṣù kìn-ín-ní ni kí ó gbé Àgọ́ náà, àgọ́ àjọ náà ró Gbé àpótí ẹ̀rí sí inú rẹ̀, kí ó sì bo àpótí náà pẹ̀lú aṣọ títa Gbé tábìlì náà wọ ilé, kí o sì tò àwọn ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lé e lórí Nígbà náà gbé ọ̀pá fìtílà wọlé, kí o sì to àwọn fìtílà rẹ̀ Gbé pẹpẹ wúrà ti tùràrí sí iwájú àpótí ẹ̀rí, kí o sì fi aṣọ títa ẹnu ọ̀nà sí ara àgọ́ náà Gbé pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun sí iwájú ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà, Àgọ́ àjọ gbé agbada sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, kí o sì fi omi sí inú rẹ̀ Gbé àgbàlá ró yìí ka, kí ó sì fi aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára Àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀ yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀sọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́ Ta òróró sára pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ya pẹpẹ náà sí mímọ́, yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ Ta òróró sára agbada náà àti ẹsẹ̀ rẹ, kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ Mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì wẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omi Nígbà náà wọ Árónì ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ńi orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀ Mósè ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ìn-ní ní ọdún kejì Nígbà tí Mósè gbé Àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí Àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí Àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún un Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́ ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un Mósè gbé tábìlì sínú àgọ́ àjọ sí ìhà àríwá àgọ́ náà lẹ́yìn aṣọ títa, ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa , gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òkánkán tábìlì ní ìhà gúsù Àgọ́ náà Ó sì tan àwọn fítìlà náà níwájú Olúwa , gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un Mósè gbé pẹpẹ wúrà sínú Àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́, àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ́ , gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un Ó gbé agbada sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀, Mósè, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkugbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Mósè sì gbé àgbàlá tí ó yí Àgọ́ náà kà ró àti pẹpẹ, ó sì ta aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà sí àgbàlá náà Bẹ́ẹ̀ Mósè ṣe parí iṣẹ náà Nígbà náà ni àwọ̀ọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo Olúwa bo Àgọ́ náà Mósè kò sì lè wọ inú Àgọ́ àjọ, nítorí àwọ́ọ́sánmọ̀ wà lórí rẹ, ògo Olúwa sì ti kún inú Àgọ́ náà Ní gbogbo ìrìnàjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbàkugbà tí a ba ti fa ikuuku àwọ̀ọsánmọ̀ náà sókè kúrò lórí Àgọ́, wọ́n máa ń jáde lọ ṣùgbọ́n tí àwọ̀ọsánmọ̀ kò bá gòkè wọn kò ní jáde títí di ọjọ́ tí ó bá gòkè Nítorí náà àwọ̀ọsánmọ̀ Olúwa wà lórí Àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọ̀ọsánmọ̀ ní òru, ní ojú gbogbo ilé Ísírẹ́lì ní gbogbo ìrìnàjò wọn Bíríkì Ṣíṣun Láìsí Koríko Gbígbẹ Lẹ́yìn náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, wọ́n sì wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù   Fáráò dáhùn wí pé, Ta ni Olúwa , tí èmi yóò fi gbọ́ràn sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Ísírẹ́lì ó lọ Èmi kò mọ Olúwa , èmi kò sì ní jẹ́ kí Ísírẹ́lì ó lọ Lẹ́yìn náà ni wọ́n wí pé, Ọlọ́run àwọn Hébérù tí pàdé wa Ní ìsinsìnyìí, jẹ́ kí a lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ihà láti rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run wa, kí ó má ba á fi àjàkálẹ̀-àrùn tàbí idà bá wa jà Ṣùgbọ́n ọba Éjíbítì sọ wí pé, Mósè àti Árónì, èése ti ẹ̀yin fi mú àwọn ènìyàn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn Ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́ yín Nígbà náà ni Fáráò sọ pé, Ẹ wò ó àwọn ènìyàn náà ti pọ̀ sí ì nílẹ̀ yìí ní ìsinsìnyìí, ẹ̀yin sì ń dá wọn dúró láti máa bá iṣẹ́ lọ Ní ọjọ́ yìí kan náà ni Fáráò pàṣẹ fún àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn ti ń ṣe alábojútó iṣẹ́ lórí àwọn ènìyàn Ẹ̀yin kò ní láti pèsè koríko gbígbẹ fún bíríkì síṣun mọ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí ẹ jẹ́ kí wọn máa wá koríko gbígbẹ fún ara wọn Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn ó ṣe iye bíríkì kan náà bí ì ti àtẹ̀yìnwá, kí ẹ má ṣe dín iye rẹ̀ kú Ọ̀lẹ ni wọ́n, ìwà ọ̀lẹ yìí náà ló mú wọn pariwo pé, Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rúbọ sí Ọlọ́run wa Ẹ mú iṣẹ́ náà le fún wọn, kí wọn bá a le è tẹramọ́ iṣẹ́ wọn, ẹ má fi ààyè gba irọ́ wọn Ní ìgbà náà ni àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ jáde tọ̀ wọ́n lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, Èyí ni ohun tí Fáráò sọ, Èmi kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ mọ́ Ẹ lọ wá koríko gbígbẹ ni ibi tí ẹ bá ti lè rí i, ṣùgbọ́n iṣẹ́ yín kí yóò dínkù   Gbogbo wọn sí fọ́n káàkiri ni ilẹ̀ Éjíbítì láti sa ìdì koríko tí wọn yóò lò bí ì koríko gbígbẹ fún sísun bíríkì Àwọn akóniṣiṣẹ́ sì ń ni wọ́n lára, wọ́n wí pé, Ẹ parí iṣẹ́ tí ẹ ni láti se fún ọjọ́ kan bí ìgbà ti a ń fún un yin ní koríko gbígbẹ Àwọn alábojútó iṣẹ́ tí àwọn akóniṣiṣẹ́ yàn lára ọmọ Ísírẹ́lì ni wọn ń lù, tí wọn sì ń béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Èéṣe tí ẹ̀yin kò ṣe iye bíríkì ti ẹ̀yin ń ṣe ní àná ní òní bí i tí àtẹ̀yìnwá Nígbà náà ni àwọn alábojútó iṣẹ́ tí a yàn lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tọ Fáráò lọ láti lọ bẹ̀bẹ̀ pé, Èéṣe tí ìwọ ti fi ọwọ́ líle mú àwa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ báyìí Wọn kò fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni koríko gbígbẹ, ṣíbẹ̀ wọn sọ fún wa pé, Ẹ ṣe bíríkì! Wọ́n na àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀bi náà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ Fáráò sí dáhùn wí pé, Ọ̀lẹ niyín, ọ̀lẹ! Èyí ni ó mú kí ẹ̀yin máa sọ ni ìgbà gbogbo pé, Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rúbọ sí Olúwa Nísínsìnyìí ẹ padà lọ sí ẹnu iṣẹ́ yín, a kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ, ṣíbẹ̀ ẹ gbọdọ̀ ṣe iye bíríkì tí ó yẹ kí ẹ ṣe Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ mọ̀ dájú wí pé àwọn ti wà nínú wàhálà ńlá ní ìgbà tí a sọ fún wọn pé, Ẹ kò ní láti dín iye bíríkì tí ẹ ń ṣe ni ojoojúmọ́ kù Ní ìgbà tí wọ́n kúró ni ọ̀dọ̀ Fáráò wọ́n rí Mósè àti Árónì tí ó dúró láti pàdé wọn Wọn sì wí pé, Kí Olúwa kí ó wò yín, kí ó sì ṣe ìdájọ́! Ẹ̀yin ti mú wa dàbí òórùn búburú fún Fáráò àti àwọn òsìṣẹ̀ rẹ̀, ẹ sì ti fún wọn ni ìdà láti fi pa wá Mósè padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, Olúwa , èéṣe tí ìwọ fi mú ìyọnu wá sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí Ṣe torí èyí ni ìwọ fi rán mi Láti ìgbà ti mo ti tọ Fáráò lọ láti bá a sọ̀rọ̀ ni orúkọ rẹ ni ó ti mú ìyọnu wá sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì gba àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ rárá Àkọsílẹ̀ Ìdílé Mósè Àti Árònì Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mósè pé, Ní ìsin yìí, ìwọ yóò rí ohun tí èmi yóò ṣe sí Fáráò pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi ni yóò fi jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi, òun yóò lé wọn jáde kúró ní orílẹ̀ èdè rẹ̀ Ọlọ́run sì tún sọ fún Mósè pé, Èmi ni Olúwa Mo fi ara hàn Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù bí Ọlọ́run alágbára ṣùgbọ́n nípa orúkọ mi Olúwa , Èmi kò fi ara mi hàn wọ́n Èmí sì tún fi idi májẹ̀mu mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kénánì, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjòjì Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àwọn tí àwọn ará Éjíbítì mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mu mi Sọ fún àwọn ará ilé Ísírẹ́lì Èmi ni Olúwa , Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúró nínú àjàgà àwọn ará Éjíbítì Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúró ní oko ẹrú wọn Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá Èmi yóò mú un yín bí ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ̀ Ọlọ́run yín Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde kúró nínú àjàgà àwọn ará Íjíbítí Èmi yóò mú un yín wá ilẹ̀ náà ti èmi ti búra pẹ̀lú ìgbọ́wọ́sókè láti fi fún Ábúráhámù Ísáákì àti Jákọ́bù Èmi yóò fi fún un yín bí ohun ìní, èmi ni Olúwa   Mósè sì sọ èyí fún àwọn ará Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọn kò fi etí sílẹ̀ sí Mósè nítorí ọkàn wọn tó rẹ̀wẹ̀sì àti nítorí ìgbékùn búburú bí ohun tí ó ti kọ́ sọ kó wọn sí ní oko ẹrú wọn Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè Lọ, sọ fún Fáráò ọba Éjíbítì pé kí ó jẹ́ kí àwọn ará Ísírẹ́lì lọ kúró ní orílẹ̀ èdè rẹ̀ Ṣùgbọ́n Mósè sọ fún Olúwa pé, Nígbà ti àwọn ará Ísírẹ́lì tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Fáráò yóò se fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò Olúwa bá ìran Mósè àti Árònì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Ísírẹ́lì àti Fáráò ọba Íjibítì, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì Wọ̀nyí ni olórí ìran wọn Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àkọ́bí Ísírẹ́lì ni Hánókù, Pálù, Hésúrónì àti Kámì Àwọn wọ̀nyí ni ìdílé Rúbẹ́nì Àwọn ọmọ Ṣímóní ní Jémúẹ́lì, Jámì, Óhádì, Jákínì, Ṣóhárì àti Ṣọ́ọ̀lù ọmọ obìnrin Kénánì Àwọn wọ̀nyí ni ìran Símónì Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn Gésónì, Kóhábì àti Mérárì Léfì lo ẹ̀tàndínlógóje ọdún láyé Àwọn ọmọ Gésónì ni ìran wọn ni Líbínì àti Ṣímẹ́lì Àwọn ọmọ Kóhátì ni Ámírámù, Ísárì, Hébírónì àti Yúsíélì Kóhátì lo ẹ̀tàléláádóje ọdún láyé Àwọn ọmọ Mérárì ni Máhílì àti Músíhì Ìwọ̀nyí ni ìran Léfì gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn Ámírámù sì fẹ́ Jókébédì arákùnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó Jókébédì sì bí Árónì àti Mósè fún un Ámírámù lo ẹ̀tàdínlógóje ọdún láyé Àwọn ọmọ Ísárì ni Kórà, Nẹ́fẹ́fì àti Ṣíkírì Àwọn ọmọ Yúṣíélì ni Míṣíháẹlì, Élíṣáfánì àti Ṣítíhírí Árónì fẹ́ Élíṣahẹ́ba ọmọbìnrin Ámínádábù tí í ṣe arábìnrin Náhísíhónì, ó sì bí Nádábù, Ábíhù, Élíásárì àti Ítamárì Àwọn ọmọ Kórà ni Ásírì, Élíkánà àti Ábíásáfù, ìwọ̀nyí ni ìran Kórà Élíásárì ọmọ Árónì fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Pútíẹ́lì ní ìyàwó, ó sì bí Fínéhásì fún un Ìwọ̀nyí ni olórí àwọn Léfì ni ìdílé ìdílé Árónì àti Mósè yìí kan náà ni Olúwa sọ fún pé, Ẹ kó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí Àwọn ni ó bá Fáráò ọba Éjíbítì sọ̀rọ̀ nípa kíkó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni Éjíbítì, àní Mósè àti Árónì yìí kan náà ni Nígbà tí Olúwa bá Mósè sọ̀rọ̀ ni Éjíbítì, Ó ni Èmi ni Olúwa Sọ ohun gbogbo ti mo ti sọ fún ọ fún Fáráò ọba Éjíbítì Ṣùgbọ́n Mósè sì wí ní iwájú Olúwa pé, Níwọ̀n ìgbà ti mo jẹ́ akólòlò, ọ̀nà dà ti Fáráò yóò ṣe fi etí sí mi Ọ̀pá Mósè di ejò Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Wò ó, èmi ti ṣe ọ bí Ọlọ́run fún Fáráò, Árónì arákùnrin rẹ ni yóò jẹ́ wòlíì rẹ Ìwọ yóò sì sọ ohun gbogbo tí èmi ti pàṣẹ fún ọ, Árónì arákùnrin rẹ yóò sí sọ fún Fáráò kí ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ rẹ̀ Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣé Fáráò lọ́kàn le Bí mo tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu ni Éjíbítì, ṣíbẹ̀ òun kì yóò fi etí sí ọ Nígbà náà ni èmi yóò gbé ọwọ́ mi lé Éjíbítì, pẹ̀lú agbára ìdájọ́ ńlá mi ni èmi yóò mú àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì jáde ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ Àwọn ará Éjíbítì yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa ní ìgbà tí mo bá na ọwọ́ mi jáde lé Éjíbítì, tí mo sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò níbẹ̀ Mósè àti Árónì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ́ fún wọn Mósè jẹ́ ọmọ ọgọ́rin ọdún Árónì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́talélọ́gọ́rin ni ìgbà tí wọ́n bá Fáráò sọ̀rọ̀ Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì, Ní ìgbà tí Fáráò bá sọ fún un yín pé, Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan, sọ fún Árónì ní ìgbà náà pé, Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ níwájú Fáráò, yóò sì di ejò Nígbà náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, wọ́n sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn, Árónì ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ ní ìwájú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò Fáráò sì pe àwọn amòye, àwọn osó àti àwọn onídán ilẹ̀ Éjíbítì jọ, wọ́n sì fi idán wọn ṣe ohun tí Mósè àti Árónì ṣe Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò Ṣùgbọ́n ọ̀pá Árónì gbé ọ̀pá tiwọn mì Ṣíbẹ̀ ọkàn Fáráò sì yigbì, kò si fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Ọkàn Fáráò ti di líle, ó kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà ó lọ Tọ Fáráò lọ ni òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ó ti ń lọ sí etí odò, dúró ni etí bèbè odò Náílì láti pàdé rẹ, mú ọ̀pá rẹ tí ó di ejò ni ọwọ́ rẹ Sọ fún un pé, Olúwa Ọlọ́run àwọn Hébérù rán mi sí ọ láti sọ fún ọ pé Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè sìn mi ni ihà Ṣùgbọ́n títí di àkókò yìí, ìwọ kò gba Èyí ni Olúwa wí Nípa èyí ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Wò ó, èmi yóò fi ọ̀pá ti ó wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò ná omi tí ó wà nínú odò Náìlì yóò sì di ẹ̀jẹ̀ Àwọn ẹja tí ó wà nínú odò Náìlì yóò kú, odò náà yóò sì máa rùn, àwọn ará Éjíbítì kò sì ni lè mu omi rẹ̀   Olúwa sọ fún Mósè, Sọ fún Árónì, Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì na ọwọ́ rẹ jáde lórí àwọn omi Éjíbítì Lórí àwọn odò kéékèèke àti odò ńlá, lórí àbàtà àti adágún omi wọn yóò sì di ẹ̀jẹ̀ Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ni ibi gbogbo ni Éjíbítì, àní nínú ọpọ́n àti nínú kete omi àti nínú ìkòkò tí a pọn omi sí nínú ilé Mósè àti Árónì sí ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn Ó gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ni ìwájú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì lu omi odò Náìlì, omi odò náà sì yípadà sí ẹ̀jẹ̀ Ẹja inú odò Náìlì sì kú, odò náà ń rùn gidigidi tí ó fi jẹ́ pé àwọn ará Éjíbítì kò le è mu omi inú rẹ̀ Ẹ̀jẹ̀ sì wà ni ibi gbogbo ni ilẹ̀ Éjíbítì Ṣùgbọ́n àwọn apidán ilẹ̀ Éjíbítì sì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, ọkàn Fáráò sì yigbì ṣíbẹ̀ kò sì fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Dípò bẹ́ẹ̀, ó yíjú padà, ó sì lọ sí ààfin rẹ̀, kò sì jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí wà ni oókan àyà rẹ̀ Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará Éjíbítì bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ etí odò Náílì láti wá omi tí wọn yóò mu, nítorí wọn kò le è mu omi tí ó wà nínú odò náà Ọjọ́ Méje sì kọjá ti Olúwa ti lu Odò Náílì Kòròrò bo ilẹ̀ Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Padà tọ Fáráò lọ kí ó sì sọ fún un pé, Èyí ni Olúwa wí Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn ó bá à lè sìn mi Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, èmi yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀pọ̀lọ́ kọ lu gbogbo orílẹ̀ èdè rẹ Odò Náílì yóò kún fún ọ̀pọ̀lọpọ́ àwọn ọ̀pọ̀lọ́ Wọn yóò gókè wá sí ààfin rẹ, àti yàrá rẹ ni orí ìbùsùn rẹ Wọn yóò gòkè wá sí ilé àwọn ìjòyè rẹ àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ, àti sí ibi ìdáná rẹ, àti sí inú ìkòkò ìyẹ̀fun rẹ Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóò gun ara rẹ àti ara àwọn ìjòyè rẹ, àti ara gbogbo àwọn ènìyàn rẹ   Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún Árónì, Kí ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde pẹ̀lú ọ̀pá sí orí àwọn odò kékèké àti odò ńlá, àti sí orí àwọn àbàtà kí ó sì mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ gòkè wá sí ilẹ̀ Íjíbítí   Ní ìgbà náà ni Árónì sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí àwọn omi Éjíbítì, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì wá, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn onídan ilẹ̀ Éjíbítì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn Àwọn náà mú kí ọ̀pọ̀lọ́ gun wá sí orí ilẹ̀ Éjíbítì Fáráò ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì, ó sì sọ fún wọn pé, Gbàdúrà sí Olúwa kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí kúrò lọ́dọ̀ mi àti lára àwọn ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ kí ó lọ láti rúbọ sí Olúwa Mósè sọ fún Fáráò pé, Jọ̀wọ́ sọ fún mi ìgbà ti èmi yóò gbàdúrà fún ọ àti àwọn ìjòyè rẹ àti fún àwọn ènìyàn rẹ, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí bá lè lọ lọ́dọ̀ rẹ àti ní àwọn ilé yín tí wọn yóò sì wà nínú odò Náílì nìkan Fáráò wí pé, Ni ọ̀lá Mósè sì dáhùn pé, Yóò sì rí bí ìwọ ti sọ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni bí Olúwa Ọlọ́run wa Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóò fi ìwọ àti àwọn ilé yín àti ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, wọn yóò sì wà nínú Náìlì nìkan Lẹ́yìn tí Mósè àti Árónì tí kúrò ní ìwájú Fáráò, Mósè gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sókè sí Olúwa nípa àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí ó ti ran sí Fáráò Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè tí béèrè Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì kú nínú ilé àti ní ìta, gbangba àti nínú oko Wọ́n sì kó wọn jọ ni okíti okíti gbogbo ilẹ̀ sì ń rùn Ṣùgbọ́n ni ìgbà tí Fáráò rí pé ìtura dé, ó sé ọkàn rẹ̀ le kò sì fetí sí Mósè àti Árónì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún Árónì, Na ọ̀pá rẹ jáde kí ó sì lu eruku ilẹ̀, jákè jádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì ni erùpẹ̀ ilẹ̀ yóò ti di kòkòrò-kantíkantí Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, Nígbà tí Árónì na ọwọ́ rẹ́ jáde pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì lu eruku ilẹ̀, kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko wọn Gbogbo eruku jákè-jádò ilẹ̀ Éjíbítì ni ó di kòkòrò-kantíkantí Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn onídán gbìdánwò láti da kòkòrò-kantíkantí pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, wọn kò le è ṣé Kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ẹranko wọn Àwọn onídán sì sọ fún Fáráò pé, Ìka Ọlọ́run ni èyí Ṣùgbọ́n àyà Fáráò sì yigbì, kò sì fetí sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí o sì ko Fáráò lójú bí ó ṣe ń lọ sí odò, kí o sì sọ fún un pé, Èyí ni Olúwa sọ Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó bá à lè sìn mi Bí ìwọ kò bá jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, èmi yóò rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sí ara rẹ àti sí ara àwọn ìjòyè rẹ, àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ̀, sí àwọn ilẹ̀ rẹ̀ Gbogbo ilé àwọn ará Éjíbítì ni yóò kún fún eṣinṣin àti orí ilẹ̀ tí wọ́n wà pẹ̀lú  Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ náà, èmi yóò ya ilẹ̀ Góṣénì sọ́tọ̀, níbi tí àwọn ènìyàn mi ń gbé, ọ̀wọ́ eṣinṣin kankan ki yóò dé ibẹ̀ Kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, èmi ni Olúwa , mo wà ni ilẹ̀ yìí Èmi yóò pààlà sáàárin àwọn ènìyàn mi àti àwọn ènìyàn rẹ Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí yóò ṣẹlẹ̀ ni ọ̀la   Olúwa sì ṣe èyí Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sì ya wọ ààfin Fáráò àti sí ilé àwọn ìjòyè rẹ̀ Gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì bàjẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ̀n-ọn-nì Nígbà náà ni Fáráò ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ máa lọ kí ẹ sì rúbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé, Èyí ló tọ́, ẹbọ tí a ó rú sí Olúwa Ọlọ́run wa yóò jẹ́ ohun ìríra sí àwọn ará ilẹ̀ Éjíbítì Bí a bá ṣe ìrúbọ ti yóò jẹ́ ìríra ni ojú wọn ṣé wọn kò ní sọ òkúta lù wá A gbọdọ̀ lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú ihà láti rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wa Nígbà náà ni Fáráò wí pé, Èmi yóò jẹ́ ki ẹ lọ rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín nínú ihà, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rìn jìnnà jù Ẹ gbàdúrà fún mi Mósè dáhùn ó wí pé, Bí èmi bá ti kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa , awọn esinsin yóò fi Fáráò, àwọn ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ ní ọ̀la ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìdánílójú wa pé Fáráò kò tún ni lo ẹ̀tàn láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn kí ó lọ rú ẹbọ sí Olúwa Nígbà náà ni Mósè kúrò ni ọ̀dọ̀ Fáráò, ó sì gbàdúrà sí Olúwa Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè ti béèrè Àwọn esinsin kúrò lára Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti lára àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú, esinsin kan kò sì sẹ́kù Ṣùgbọ́n ni àkókò yìí náà, Fáráò sé ọkàn rẹ le kò sì jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ Àrùn Lára Ẹran Ọ̀sìn Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Lọ sọ fún Fáráò, Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Hébérù sọ Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn mí Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, tí ó sì dá wọn dúró Ọwọ́ Olúwa yóò mú àrùn búburú wá sí ara ẹran ọ̀sìn nínú oko, sí ara ẹsin, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, rànkunmí, màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́ yín Ṣùgbọ́n Olúwa yóò pààlà sí àárin ẹran ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti Ísírẹ́lì àti ti àwọn ara Éjíbítì tí yóò fi jẹ́ pé kò sí ẹran ọ̀sìn ti ó jẹ́ ti ará Ísírẹ́lì tí yóò kú   Olúwa sì dá àkókò kan wí pé, Ní ọ̀la ni Olúwa yóò ṣe èyí ni ilẹ̀ yìí Olúwa sí ṣe é ni ọjọ́ kejì Gbogbo ẹran-ọ̀sìn ará Éjíbítì kú, ṣùgbọ́n ẹyọkan kò kú lára ẹran-ọ̀sìn àwọn Ísírẹ́lì Fáráò rán àwọn ènìyàn rẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí, wọ́n sì rí pé ẹyọkan kò kú lára àwọn ẹran ọ̀sìn ará Ísírẹ́lì Ṣíbẹ̀ náà, Fáráò kò yí ọkàn rẹ̀ padà àti pé kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì, Ẹ bu ẹ̀kúnwọ́ eérú gbígbóná láti inú ààrò, kí Mósè kù ú sí inú afẹ́fẹ́ ni iwájú Fáráò Yóò sì di eruku lẹ́búlẹ́bú ni gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, yóò sì di oówo ti ń tú pẹ̀lú ìléròrò sí ara àwọn ènìyàn àti ẹran jákè jádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Fáráò Mósè sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran Àwọn onídán kò le è dúró níwájú Mósè nítorí oówò ti ó wà lára wọn àti ni ara gbogbo àwọn ara Éjíbítì Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sé ọkàn Fáráò le, kò sì gbọ́ ti Mósè àti Árónì, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mósè Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Dìde ni òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí o sì tọ Fáráò lọ, kí o sì wí fún un pé, Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Hébérù wí Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sin mí, Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò rán ìdààmú ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọ lù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ohun búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀ Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe dá ọ sí, kí èmi kí ó lè fi agbára mi hàn ọ́, kí a bá à lè gbọ́ òkìkí orúkọ mi ní gbogbo ayé Ṣíbẹ̀ ìwọ tún gbógun ti àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì jẹ́ kí wọn lọ Nítorí náà, ni ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán òjò o yìnyín tí irú rẹ̀ kò tí i rọ̀ rí ni Éjíbítì láti ìpìlẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di àkókò yìí Pàṣẹ nísin yìí láti kó ẹran-ọ̀sìn yin àti ohun gbogbo ti ẹ ni ní pápá wá sí abẹ́ ààbò, nítorí òjò yìnyín yóò rọ̀ sí orí àwọn ènìyàn àti ẹran ti a kò kó wá sí abẹ́ ààbò tí wọ́n sì wà ni orí pápá, wọn yóò sì kú   Àwọn ti ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Olúwa lára àwọn ìjòyè Fáráò yára lọ láti kó àwọn ẹrú àti àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn wá sí abẹ́ ààbò Ṣùgbọ́n àwọn ti kò kà ọ̀rọ̀ Olúwa sí fi àwọn ẹrú wọn àti àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ni pápá Olúwa sọ fún Mósè pé, Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ọ̀run kí yìnyín bá à lè rọ̀ sí orí gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, sí orí ènìyàn àti ẹranko, àti sí orí gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko Nígbà tí Mósè gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, Olúwa rán àrá àti yìnyín, mọ̀nàmọ́ná sì bù sí orí ilẹ̀ Olúwa rọ òjò yìnyín sí orí ilẹ̀ Éjíbítì Yìnyín rọ̀, mọ̀nàmọ́ná sì bẹ̀rẹ̀ sí bù sí orí ilẹ̀ èyí ni ó tí ì buru jù ti ó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ti Éjíbítì ti di orílẹ̀ èdè Jákè jádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì ni yìnyín ti pa gbogbo ohun tí ó wà ni orí pápá ènìyàn àti ẹranko, ó wò gbogbo ohun ọ̀gbìn lulẹ̀ ó sì fa gbogbo igi ya pẹ̀lú Ilẹ̀ Gósénì ni ibi ti àwọn Ísírẹ́lì wà nikan ni òjò yìnyín náà kò rọ̀ dé Nígbà náà ni Fáráò pe Mósè àti Árónì sì ọ̀dọ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, Èmi ti ṣẹ̀ ní àkókò yìí Olúwa jẹ́ olódodo ṣùgbọ́n èmi àti àwọn ènìyàn mi ni aláìsòdodo Èyí ti òjò yìnyín àti àrá rọ̀ yìí tó gẹ́ẹ́, gbàdúrà sí Olúwa kí ó dáwọ́ rẹ̀ dúró Èmi yóò jẹ́ kí ẹ lọ, n kò tún ni dá a yín dúró mọ́ Mósè dá a lóhùn pé, Bí mo bá ti jáde kúró ní àárin ilú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí Olúwa , sísàn àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé Olúwa ni ó ni ilẹ̀ Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ kò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run kò bàjẹ́, èṣo wọn padà gbó nítorí wọ́n máa ń pẹ so) Nígbà náà ni Mósè kúrò ni iwájú Fáráò, ó kúrò ni àárin ìgboro kọjá lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Olúwa , sísán àrá àti òjò yìnyín ti ń rọ̀ sì dáwọ́ dúró, òjò kò sì rọ̀ sí orí ilẹ̀ mọ́ Nígbà tí Fáráò rí i pé òjò àti yìnyín àti àrá ti ń sán ti dáwọ́ dúró, ó tún ṣè ní ẹ̀ẹ̀kan sí i Ọkan Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ yigbì Ọkàn Fáráò sì yigbì, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó lọ, bí Olúwa ti sọ láti ẹnu Mósè Ẹ̀dá Alààyè Àti Ògo Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹrin tí mo di ọmọ ọgbọ̀n ọdún tí mo wà láàrin àwọn ìgbèkùn ní etí òdò Kébárì, àwọn ọ̀run sí sílẹ̀, mo sì rí ìran Ọlọ́run Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù—tí ó jẹ́ ọdún karùn-ún ìgbèkùn Ọba Jehóákímù— ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ àlùfáà Ísíkẹ́lì, ọmọ Búsì wá, létí odò Kébárì ni ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì Níbẹ̀ ni ọwọ́ Olúwa ti wà lára rẹ̀ Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùukùu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká Àárin iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná, àti láàrin iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin wà Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin Ẹsẹ̀ wọn sì tọ́ àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì rí bí ti ọmọ màlúù, wọ́n sì tàn bí awọ idẹ dídán Ní abẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ní ọwọ́ ènìyàn Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú àti àwọn ìyẹ́, ìyẹ́ wọn kan ara wọn Bẹ́ẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò padà lọ́nà ibi tí ó ń lọ ṣùgbọ́n wọ́n ń lọ tààrà ni Báyìí ni ìrísí ojú àwa ẹ̀dá alààyè yìí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú ènìyàn, ní apa ọ̀tún wọn, wọ́n ní ojú kìnnìún ní ìhà ọ̀tún, wọ́n ní ojú màlúù ní ìhà òsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n sì tún ní ojú ẹyẹ idì Báyìí ni àpèjúwe ojú wọ́n Ìyẹ́ wọn gbé sókè ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ méjì, ìyẹ́ ọ̀kan sì kan ti èkejì ni ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ìyẹ́ méjì tó sì tún bo ara wọn Olúkúlùkù wọn ń lọ tààrà Níbikíbi tí èmi bá ń lọ, ni àwọn náà ń lọ, láì wẹ̀yìn bí wọ́n ti ń lọ Ìrísí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí dàbí ẹyin iná tí ń jó tàbí bí i iná tọ́ọ̀sì Iná tó ń jó ń lọ sókè lọ sódò láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè iná yìí mọ́lẹ̀ rokoṣo, ó sì ń bù yẹ̀rì yẹ̀rì jáde lára rẹ̀ Àwọn ẹ̀dá alààyè yìí sì ń sáré lọ sókè lọ sódò bí i ìtànsán àrá Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè yìí, mo rí kẹ̀kẹ́ ní ilẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí pẹ̀lú ojú rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin Àpèjúwe àti ìrísí àwọn kẹ̀kẹ́ náà nìyìí kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rí bákan náà, wọ́n sì ń tàn yinrin yinrin bí i kírísólétì, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kẹ̀kẹ́ yìí rí bí i ìgbà tí a fi kẹ̀kẹ́ bọ kẹ̀kẹ́ nínú Àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń yí bí wọ́n ti ń yí, wọ́n ń lọ tààrà síbi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè kọjú sí, kẹ̀kẹ́ wọn kò sì yapa bí àwọn ẹ̀dá náà ti n lọ Àwọn ríìmù wọ́n ga, wọ́n sì ba ni lẹ́rù, àwọn ríìmù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jẹ́ kìkìdá ojú yíká Bí àwọ́n ẹ̀dá bá ń rìn, kẹ̀kẹ́ ẹgbẹ wọn náà yóò rìn, bí wọ́n fò sókè, kẹ̀kẹ́ náà yóò fò sókè Ibikíbi tí ẹ̀mi bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ wọn yóò sì bá wọn lọ, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú kẹ̀kẹ́ wọn Bí àwọn ẹ̀dá yìí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ náà yóò lọ bí wọ́n bá dúró jẹ́ẹ́ kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni bí àwọn ẹ̀dá yìí bá dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí yóò dìde pẹ̀lú wọn, nítorí pé ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí wà nínú àwọn kẹ̀kẹ́ Ohun tí ó dàbí òfuurufú ràn bo orí àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí, ó ń tàn yinrin yinrin bí i yìnyín, ó sì ba ni lẹ́rù Ìyẹ́ wọn sì ń kan ara wọn lábẹ́ òfuurufú yìí, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìyẹ́ méjì méjì tó bo ara wọn Nígbà tí àwọn ẹ̀dá náà gbéra, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn tó bolẹ̀ bí i ríru omi, bí i ohùn Olódùmarè, bí i híhó àwọn jagunjagun Nígbà tí wọ́n dúró jẹ́ẹ́, wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀ Bí wọ́n ṣe dúró tí wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀, ohùn kan jáde láti inú òfuurufú tó rán bò wọ́n Lókè àwọ̀ òfuurufú tó borí wọn yìí ni ohun tí ó ní ìrísí ìtẹ́ Ìtẹ́ náà dàbí òkúta Sáfírè, lókè ní orí ìtẹ́ ní ohun tó dàbí ènìyàn wà Láti ibi ìbàdí ènìyàn náà dé òkè, o dàbí irin tí ń kọ yànrànyànràn O dàbí pe kìkì iná ni, láti ibi ìbàdí rẹ dé ìsàlẹ̀ dàbí iná tó mọ́lẹ̀ yí i ká Ìmọ́lẹ̀ tó yí i ká yìí dàbí ìrísí òṣùmàrè tó yọ nínú ìkuukùu nígbà tí òjò bá rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ tò yí i ká Báyìí ni ìrísí ògo Olúwa Nígbà tí mo rí i, mo dojú bolẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn ẹnìkan tó ń sọ̀rọ̀ Ògo Kúrò Nínú Tẹ́ḿpìlì Mo sì wò ó, mo rí ohun kan tó dàbí òkúta sáfírè nínú òfuurufú tó wà lókè orí kérúbù, ìrísí ohun yìí sì dàbí ìtẹ́ Olúwa sì sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun pé, Lọ sí àárin àwọn kẹ̀kẹ́ tó wà lábẹ́ kérúbù Bu ẹyin iná tó kúnwọ́ rẹ láàrin kérúbù, kí o sì fọ́n-ọn sórí ìlú náà Ó sì lọ lóju mi Àwọn kérúbù dúró sí apá gúúsù tẹ́ḿpìlì nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìkùukùu sì bo inú àgbàlá Ògo Olúwa sì kúrò lórí àwọn kérúbù, ó bọ́ sí ibi ìloro tẹ́ḿpìlì Ìkùukùu sì bo inú tẹ́ḿpìlì, àgbàlá sì kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ògo Olúwa A sì gbọ́ ariwo ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí títí dé àgbàlá tó wà níta gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmáre bá ń sọ̀rọ̀ Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún ọkùnrin aláṣọ funfun yìí pé, Mú iná láàrin àwọn kẹ̀kẹ́, láàrin àwọn kérúbù, ó sì lọ dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ náà Ọ̀kan nínú àwọn kérúbù sì nawọ́ síbi iná tó wà láàrin kérúbù yóòkù Ó mú lára rẹ, ó fi sínú ọwọ́ ọkùnrin aláṣọ funfun, òun náà gbàá, ó sì jáde lọ Mo sì rí i pé kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù yìí, kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kọ̀ọ̀kan àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń tàn yanran bí àpapọ̀ àwọ̀ ewéko àti pupa rẹ́súrẹ́sú Ní ti ìrísí wọn, gbogbo wọn jọra wọn ọ̀kọ̀ọ̀kan rí bí ìgbà tí kẹ̀kẹ́ kan wà nínú kẹ̀kẹ́ mìíràn Nígbà tí wọ́n ń lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀kan nínú ọ̀nà mẹ́rin tí àwọn kérúbù dojú kọ àwọn kẹ̀kẹ́ náà kò yípadà bí àwọn kérúbù ti ń lọ Àwọn kérúbù ń lọ síbi tí orí dojú kọ láì yà Gbogbo ara wọn àti ẹ̀yìn, ọwọ́ àti ìyẹ́ wọn àwọn kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ló ní ojú tó yí wọn ká Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ni kẹ̀kẹ́ ìpòòyì Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kérúbù yìí ni ojú mẹ́rin ojú èkínní jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì jẹ́ ti ènìyàn, ojú kẹta jẹ́ ti kìnnìún nígbà tí ojú kẹrin jẹ́ ti ẹyẹ idì A gbé àwọn kérúbù sókè Èyí ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí létí odò Kébárì Bí àwọn kérúbù yìí bá ń lọ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹgbẹ́ wọn náà yóò lọ bẹ́ẹ̀ ni bí àwọn kérúbù bá tú ìyẹ́ wọn ká láti dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí kò ní kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn Bí àwọn kérúbù bá dúró díẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́ bí àwọn kérúbù bá dìde àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dìde, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú wọn Ògo Olúwa kúrò níbi ìloro tẹ́ḿpìlì ó sì dúró sórí àwọn kérúbù Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé Olúwa , ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lórí wọn Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọ́run Ísírẹ́lì létí odò Kébárì, mo sì mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ mẹ́rin, lábẹ́ ìyẹ́ wọn ni ohun tó jọ ọwọ́ ènìyàn wà Àfiwé ojú àti ìrísí wọn rí bákan náà pẹ̀lú àwọn tí mo rí létí odò kébárì Olúkúlùkù wọn sì ń lọ sí ọ̀kánkán tààrà Ìdájọ́ Lórí Àwọn Àgbà Ísírẹ́lì Ẹ̀mí sì gbé mi sókè, ó mú mi lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa èyí tó dojú kọ ìlà oòrùn Ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà yìí ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n wá, mo rí Jáásáníà ọmọ Àsúrì àti Pélátíà ọmọ Bénáyà, tí wọ́n jẹ́ aláṣẹ àwọn ènìyàn Olúwa sì sọ fún mi pé, Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń pète ibi, wọ́n sì ń gba ìmọ̀ràn búburú kalẹ̀ nínú ìlú Wọ́n ní, kò ha tí ì tó àsìkò láti kọ́lé Ìlú yìí ni ìkòkò ìdáná, àwa sì ni ẹran Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé mi, ó sì wí pé, Sọ̀rọ̀! Báyìí ni Olúwa wí, Ohun tí ẹ-ń sọ níyìí, ilé Ísírẹ́lì, mo mọ ohun tó wà lọ́kàn yín Bí ẹ ṣe ń pànìyàn tún ti pọ̀ síi nínú ìlú, òkú sì ti kún gbogbo ojú pópó Torí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, àwọn òkú tí ẹ pa sáàrin yín ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò ìdáná ṣùgbọ́n n ó le yín jáde níbẹ̀ Ẹ bẹ̀rù idà, n ó sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí N ó lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, n ó sì fà yín lé àlejò lọ́wọ́, n ó sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí Nípa idà ni ẹ ó ṣubú, n ó sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Ísírẹ́lì Nígbà náà lẹ ó mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀ N ó ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Ísírẹ́lì Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa , nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀ èdè tó yí yín ká Bí mo ṣe ń sọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, Pélátíà ọmọ Bénáyà kú Mo sì dojúbolẹ̀, mo sì kígbe sókè pé, Áà! Olúwa , Ọlọ́run! Ṣé o fẹ́ pa ìyókù Ísírẹ́lì run pátapáta ni Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, àwọn arákùnrin rẹ, àní àwọn ará rẹ, àwọn ọkùnrin nínú ìbátan rẹ, àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì pátapáta, ni àwọn ará Jérúsálẹ́mù ti wí fún pé, Ẹ jìnnà sí Olúwa , àwa ni a fi ilẹ̀ yìí fún yín ní ìní Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀ èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, n ó jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ Nítorí náà, sọ pé Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Èmi yóò kó wọn jọ kúrò láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, Èmi yóò sì fún wọn ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì padà Wọn yóò padà síbẹ̀, wọn ó sì mú gbogbo àwòrán ìríra rẹ̀ àti ìbọ̀rìṣà kúrò N ó fún wọn ní ọ̀kan kan èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn N ó mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, n ó sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́ Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sórí wọn bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run wí Àwọn kérúbù sì gbé ìyẹ́ wọn sókè pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lókè orí wọn Ògo Olúwa sì gòkè lọ kúrò láàrin ìlú, ó sì dúró lórí òkè tó wà ní ìlà oòrùn ìlú náà Ẹ̀mí gbé mi sókè, ó sì mú mi lójú ìran lọ bá àwọn ìgbèkùn Bábílónì Ìran tí mo rí sì parí, Mo sì sọ gbogbo ohun tí Olúwa fihàn mí fún àwọn tó wà ní Ìgbèkùn Àpẹẹrẹ Àwọn Tó Wà Ní ìgbékùn Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, ò ń gbé láàrin ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn Wọ́n lójú láti fi ríran, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n létí láti fi gbọ́ran ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ran, torí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn, palẹ̀ ẹrù rẹ mọ́ láti lọ sí ìgbèkùn, lọ́san gangan lójú wọn, kúrò láti ibi tí o wà lọ sí ibòmíràn Bóyá bí wọ́n bá rí ọ, yóò yé wọn, wọn ó sì ronú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n Di ẹrù ìgbèkùn rẹ lójú wọn lọ́sàn án gangan, nígbà tó bá sì di alẹ́, loju wọn máa lọ sí ìgbèkùn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó lọ ìgbèkùn ṣe máa ń ṣe Dá ògiri lu lójú wọn, kí o sì gba ibẹ̀ kó ẹrù rẹ jáde Gbé ẹrù rẹ lé èjìká lójú wọn, bo ojú rẹ, kí o má ba à rí ilẹ̀, sì ru ẹrù rẹ lọ lálẹ́ nítorí pé mo fi ọ́ ṣe àmì fún ilé Ísírẹ́lì Mo ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi Mo kẹ́rù mi jáde lọ́sàn án láti lọ fun ìgbèkùn Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, mo dá ògiri lu pẹ̀lú ọwọ́ mi Mo sì gbẹ́rù mi léjìká nínú òkùnkùn lójú wọn Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, Ǹjẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé Ísírẹ́lì tilẹ̀ bi ọ́ pé, Kí lohun tó ń ṣe túmọ̀ sí Sọ fún wọn pé, Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí kan àwọn ọmọ aládé Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tó wà láàrin rẹ Sọ fún wọn, Mo jẹ́ àmì fún yín Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe sí wọn Wọn ó kó lọ sí ìgbèkùn Gẹ́gẹ́ bí ẹni ti a dè ní ìgbèkùn Ọmọ aládé tó wà láàrin wọn yóò di ẹrù rẹ lé èjìká lálẹ́ yóò sì jáde lọ, òun náà yóò da ògiri lu kí ó le gba ibẹ̀ jáde Yóò sì bo ojú rẹ̀ kí ó má ba à rí ilẹ̀ N ó ta àwọ̀n mi lé e lórí, yóò sì kó sínú okùn, N ó sì mú lọ sí Bábílónì, ní ilẹ̀ Kádíyà, ṣùgbọ́n kò ní fojú rí ilẹ̀ náà ibẹ̀ ni yóò kú sí Gbogbo àwọn tó yí i ká láti ràn án lọ́wọ́ ni N ó túká sí afẹ́fẹ́, n ó sì tún fi idà lé wọn kiri Wọn ó sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo bá tú wọn ká láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ káàkiri Ṣùgbọ́n n ó ṣẹ́ díẹ̀ kù lára wọn, lọ́wọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, kí wọn le jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe ìríra wọn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè yìí Nígbà náà ni wọn ó mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, jẹ oúnjẹ rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbọ̀n rìrì, sì mu omi rẹ pẹ̀lú ìwárìrì àti àìbalẹ̀ àyà Sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pé, Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí fún àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé Pẹ̀lú àìbalẹ̀ àyà ni wọn ó máa jẹun wọn, wọn ó sì mu omi pẹ̀lú àìnírètí, kí ilẹ̀ wọn lè di ahoro torí ìwà ipá àwọn tó ń gbé ibẹ̀ Ìlú tó jẹ́ ibùgbé ènìyàn tẹ́lẹ̀ yóò di òfo, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro Ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa   Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé Ọmọ ènìyàn, irú òwé wo lẹ ń pa nílẹ̀ Ísírẹ́lì pé A fa ọjọ́ gùn, gbogbo ìran di asán Sọ fún wọn, Èmi yóò fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní ipa mọ́ ní Ísírẹ́lì Sọ fún wọn, Ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí nígbà tí gbogbo ìran àti ìsọtẹ́lẹ̀ yóò sì wá sí ìmúṣẹ́ Nítorí kò ní sí ìran asán tàbí àfọ̀ṣẹ yẹ̀yẹ́ mọ́ láàrin ilé Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò sì ṣẹ láì falẹ̀ Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, ní àsìkò yín, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀ ilé ni Èmi yóò mú ọ̀rọ̀ yówù tí mo bá sọ ṣẹ   Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé Ọmọ ènìyàn, ilé Ísírẹ́lì ń wí pé, Ìran ọjọ́ pípẹ́ ni ó rí, ó sì sọtẹ́lẹ̀ nípa àsìkò tó jìnnà réré Nítorí náà sọ fún wọn, Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Kò sí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ mi tí yóò sún ṣíwájú mọ́ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí mo bá sọ yóò ṣẹ   Wòlíì Èké Gba Ìdálẹ́bi Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé Ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí àwọn wòlíì Ísírẹ́lì tó ń sọtẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fún àwọn tí ń sọtẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ! Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Ègbé ni fún àwọn òmùgọ̀ wòlíì tó ń tẹ̀lé ẹ̀mí ara wọn tí wọn kò sì rí nǹkankan! Ísirẹ́lì àwọn wòlíì rẹ dàbí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ nínú pápá Ẹ kò gòkè láti mọ odi tí ó ya ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì kí wọ́n ba lè dúró gbọin lójú ogun lọ́jọ́ Olúwa Ìran àti àfọ̀ṣẹ wọn jẹ́ èké Wọ́n wí pé, Olúwa wí nígbà tí Olúwa kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n fẹ́ kí Olúwa mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ Ẹ̀yin kò ha ti rí ìran asán, ẹ kò ha ti fọ àfọ̀ṣẹ èké, nígbà tí ẹ sọ pé, Olúwa wí, bẹ́ẹ̀ sì ni Èmi kò sọ̀rọ̀  Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Nítorí ọ̀rọ̀ asán àti ìran èké yín, mo lòdì sí yín ni Olúwa Ọlọ́run wí Ọwọ́ mi yóò sì wà lórí àwọn wòlíì tó ń ríran asán, tó sì ń sọ àfọ̀ṣẹ èké Wọn kò ní sí nínú ìjọ àwọn ènìyàn mi, a ó sì yọ orúkọ wọn kúrò nínú àkọsílẹ̀ ilé Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì ní wọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́ Nígbà náà ni ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run  Wọ́n ti mú àwọn ènìyàn mi sìnà, wọ́n ní, Àlàáfíà nígbà tí kò sí àlàáfíà, nítorí pé bí àwọn ènìyàn bá mọ odi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ wọn a fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, wọn ó sì fi ẹfun kùn ún, nítorí náà, sọ fún àwọn tí ń fi amọ̀ àìpò rẹ̀ ẹ àti àwọn tó fi ẹfun kùn ún pé, odi náà yóò wó, ìkún omi òjò yóò dé, N ó sì rán òkúta yìnyín sọ̀kalẹ̀, ìjì líle yóò ya á lulẹ̀ Nígbà tí odi náà bá sì wó, ǹjẹ́ àwọn ènìyàn wọn ò ní bi yín pé, Rírẹ́ tí ẹ rẹ́ ẹ dà, ibo sì ni ẹfun tí ẹ fi kùn ún wà  Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Nínú ìbínú gbígbóná mi, èmi yóò tu afẹ́fẹ́ líle lée lórí nínú ìrunú mi, àti nínú ìbínú mi, òjò yóò sì rọ̀ púpọ̀ nínú ìbínú mi, àti yìnyín ńlá nínú ìrunú mi làti pa wọ́n run Èmi yóò wó ògiri tí ẹ fi amọ̀ àìpò rẹ́, èyí tí ẹ fi ẹfun kùn lulẹ̀ débi pé ìpìlẹ̀ rẹ yóò hàn jáde Nígbà ti odi náà wó palẹ̀, a ó sì run yín sínú rẹ̀, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Báyìí ni N ó ṣe lo ìbínú mi lórí odi yìí àti àwọn to fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, tí wọ́n sì fi ẹfun kùn ún N ó sì sọ fún yín pé, Kò sí odi mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó rẹ́ ẹ náà kò sí mọ́ Àwọn wòlíì Ísírẹ́lì tí ń sọtẹ́lẹ̀ nípa àlàáfíà nígbà ti kò sì àlàáfíà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí   Nísinsin yìí, ọmọ ènìyàn, dojú kọ àwọn ọmọbìnrin ènìyàn rẹ tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn, sọtẹ́lẹ̀ sí wọn kí o sọ pé, Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Ègbé ni fún ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ń rán ìfúnpá òògùn sí ìgbọ̀nwọ́ àwọn ènìyàn, tí ẹ ń ṣe ìbòjú oríṣìíríṣìí fún orí oníkálukú ènìyàn láti sọdẹ ọkàn wọn Ẹ̀yin yóò wa dẹkùn fún ọkàn àwọn ènìyàn mi kí ẹ sì pa ọkàn yin mọ́ Nítorí ẹ̀kúnwọ́ ọkà bàbà àti èérún oúnjẹ Ẹ ti pa àwọn tí kò yẹ kí ẹ pa, ẹ sì fi àwọn tí kò yẹ kó wà láàyè sílẹ̀ nípa irọ́ tí ẹ ń pa fún àwọn ènìyàn mi, èyí tí àwọn náà ń fetí sí  Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Mo lòdì sí ìfúnpá òògùn tí ẹ fi ń ṣọdẹ ọkàn ènìyàn káàkiri bí ẹyẹ, Èmi yóò ya á kúrò lápá yín Èmi yóò sì dá ọkàn àwọn ènìyàn tí ẹ ń ṣọdẹ sílẹ̀ Èmi yóò ya àwọn ìbòjú yín, láti gba àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́ yín, wọn kò sì ní jẹ́ ìjẹ fún yín mọ́ Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Nítorí pé ẹ ti ba ọkàn àwọn olódodo jẹ́ pẹ̀lú irọ́ yín, nígbà tí Èmi kò mú ìbànújẹ́ bá wọn, àti nítorí ẹ̀yin ti mú ọkàn àwọn ènìyàn búburú le, kí wọ́n má baà kúrò nínú ọ̀nà ibi wọn débi tí wọn yóò fi gba ẹ̀mí wọn là, nítorí èyí, ẹ̀yin kò ní í ríran èké, ẹ̀yin kò sì ní fọ àfọ̀ṣẹ mọ́ Èmi yóò gba àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́ yín Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa   Àwọn Abọ̀rìṣà Gba Ìdálẹ́bì Díẹ̀ nínú àwọn alàgbà Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì jókòó níwájú mi, Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin wọnyìí ti gbé òrìṣà kalẹ̀ sínú ọkàn wọn, wọ́n sì gbé àwọn ohun tó lè mú wọn ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú wọn Ṣé ó tún yẹ kí n gbà wọ́n láàyè láti wádìí lọ́dọ̀ mi rárá bi Nítorí náà, sọ fún wọn pé Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Ísírẹ́lì tó ó gbé òrìṣà sí ọkàn wọn, tó tún gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ ṣíwájú rẹ̀, bá wá sọ́dọ̀ wòlíì, Èmi Olúwa fúnra mi ni n ó dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ N ó ṣe èyí láti gba ọkàn àwọn ará Ísírẹ́lì tó ti tẹ̀lé òrìṣà wọn lọ padà sí ọ̀dọ̀ mi Nítorí náà sọ fún ilé Ísírẹ́lì, Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí Ẹ ronú pìwàdà! Ẹ yípadà kúrò lọ́dọ̀ òrìṣà yín kí ẹ̀yin sì kọ gbogbo ìwà ìríra yín sílẹ̀!  Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Ísírẹ́lì tàbí àlejò tó ń gbé ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tó gbé òrìṣà rẹ̀ sọ́kàn rẹ̀, tó tún gbé ohun tó ń mú ni ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ ṣíwájú rẹ, lẹ́yìn èyí tó tún lọ sọ́dọ̀ wòlíì láti béèrè nǹkan lọ́wọ́ mi! Èmi Olúwa fúnra ara mi ní ń o dá a lóhùn N ó lodi si írú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lọ́nà òdì, n ó sì sọ ọ́ di àánú àti òwe Èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn mi Nígbà náà, ẹ ó mọ̀ pé èmi ni Olúwa  Bí wọ́n bá sì tan wòlíì náà láti sọtẹ́lẹ̀, Èmi Olúwa ló tan wòlíì náà, Èmi yóò nawọ́ sí i, èmi yóò sì pa á run kúrò láàrin àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì Wọn yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn—ìjìyà kan náà là ó fún wòlíì àti ẹni tó lọ béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ Kí ilé Ísírẹ́lì má baà sìnà kúrò lọ́dọ̀ mi tàbí kí wọ́n má baà sọra wọn di aláìmọ́ torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn Ṣùgbọ́n kí wọ́n le jẹ́ ènìyàn mi, kí Èmi náà sì le jẹ́ Ọlọ́run wọn, ni Olúwa Ọlọ́run wí   Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn bí orílẹ̀ èdè kan bá ṣẹ́ mí nípa ìwà àìṣòdodo, èmi yóò nawọ́ mi jáde sí wọn, láti gé ìpèsè oúnjẹ wọn, n ó rán ìyàn sí wọn, èmi yóò sì pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀, bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí—Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù-tilẹ̀ wà nínú rẹ, ará wọn nìkan ni wọ́n lé gbà sílẹ̀ pẹ̀lú ìwà òdodo wọn, ni Olúwa Ọlọ́run wí Tàbí bí mo bá jẹ́ kí ẹranko búburú gba orílẹ̀ èdè náà kọjá tí wọn fi sílẹ̀ láìní ọmọ tí wọ́n sì sọ di ahoro, tó bẹ́ẹ̀ tí kò sẹ́ni tó le gba ibẹ̀ kọjá torí ẹranko búburú yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí wà níbẹ̀ bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, wọn kò lé gba àwọn ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin wọn là, ilẹ̀ náà yóò di ahoro Tàbí tí mo bá mú idà kọjá láàrin orílẹ̀ èdè náà tí mo wí pé, Ẹ jẹ́ kí idà kọjá láàrin ilẹ̀ náà, tí mo sì tú ìbínú gbígbóná lé wọn lórí nípa ìtàjẹ́sílẹ̀, tí mo pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ Bí àwọn ọkúnrin mẹ́ta yìí tilẹ̀ wà nínú rẹ̀, Olúwa Ọlọ́run wí pé, Bí mo ti wà, wọn ki yóò gba ọmọkúnrin tàbí ọmọbìnrin là, ṣùgbọ́n àwọn tikara wọn nìkan ni a o gbàlà Tàbí bí mo rán àjàkálẹ̀-àrùn si ilẹ̀ náà, ti mo si da ìrunu mi lé e lórí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, láti gé ènìyàn àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀, bo tilẹ̀ jẹ́ pé Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù wà nínú rẹ, bí mo ti wà láàyè ni Olúwa Ọlọ́run wí wọn kò le gba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin wọn lá Ara wọn nìkan ni ìwà òdodo wọn lè gbà là Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Báwo ni yóò ti burú tó nígbà tí mo bá rán ìdájọ́ kíkan mi mẹ́rin sórí Jérúsálẹ́mù-èyí ni idà àti ìyàn, ẹranko búburú àti àjàkálẹ̀-àrùn-láti pa àwọn ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀! Síbẹ̀, yóò ṣẹ́kù àwọn díẹ̀-àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí a ó kó jáde nínú rẹ̀ Wọn yóò wá bá yin, ẹ ó rí ìwà àti ìṣe wọn, nígbà náà ni ẹ ó rí ìtùnú nípa àjálù tí mo mú wá sórí Jérúsálẹ́mù—àní gbogbo àjálù ní mo ti mú wá sórí rẹ̀ Nígbà tí ẹ bá rí ìwà àti ìṣe wọn, a ó tù yín nínú, nítorí pé ẹ ó mọ̀ pé n kò ṣe nǹkan kan láì nídìí, ni Olúwa Ọlọ́run wí Jérúsálẹ́mù, Àjàrà Tí Kò Wúlò Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, báwo ni igi àjàrà ṣe dára ju igi mìíràn lọ tàbí jù ẹ̀ka àjàrà tó wà láàrin igi yòókù nínú igbó Ǹjẹ́ a wa lè mú igi lára rẹ̀ ṣe nǹkan ti o wúlò bí Tàbí kí ènìyàn fi ṣe èèkàn tí yóò fi nǹkan kọ́ Lẹ́yìn èyí, ṣe a jù ú sínú iná gẹ́gẹ́ bí epo ìdáná, gbogbo igun rẹ̀ jóná pẹ̀lú àárin rẹ, ṣé o wà le wúlò fún nǹkan kan mọ́ Tí kò bá wúlò fún nǹkankan nígbà tó wà lódidi, báwo ni yóò ṣe wá wúlò nígbà tíná ti jó o, tó sì dúdú nítorí èéfín Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Bí mo ṣe sọ igi àjàrà tó wà láàrin àwọn igi inú igbó yóòkù di igi ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe ṣe gbogbo ènìyàn tó ń gbé Jérúsálẹ́mù Èmi yóò dojúkọ wọ́n Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ti jáde kúrò nínú iná kan síbẹ̀ iná mìíràn yóò pàpà jó wọn Nígbà tí mo bá sì dojúkọ wọ́n, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Èmi yóò sọ ilé náà di ahoro nítorí ìwà àìsòótọ́ wọn, ni Olúwa Ọlọ́run wí Òwe Nípa Àìṣododo Jérúsálẹ́mù Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, mú kí Jérúsálẹ́mù mọ gbogbo ìwà ìríra rẹ̀ Sọ pé, Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí sí Jérúsálẹ́mù Ìran rẹ àti ilẹ̀ ìbí rẹ wà ní ilẹ̀ Kénáànì ará Ámórì ni baba rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ará Hítì Ní ọjọ́ tí a bí ọ, a kò gé okùn ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fomi wẹ̀ ọ́ láti mú kí o mọ́, tàbí ká fiyọ̀ pa ọ́ lára tàbí ká fi aṣọ wé ọ Kò sẹ́ni tó ṣàánú tàbí kẹ́dùn rẹ débi àtiṣe ikankan nínú iwọ́nyi fún ọ ṣùgbọ́n lọ́jọ́ ìbí rẹ, ìta la jù ọ́ sí torí wọ́n kórìíra rẹ  Nígbà tí mo sì kọjá tí mo rí ọ tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, mo sọ fún ọ pé, Yè! Mo mú ọ dàgbà bí ohun ọ̀gbìn inú oko O ga sókè, o sì dàgbà, o wá di arẹwà jùlọ, ọmú rẹ yọ, irun rẹ gùn, ìwọ tí o wà ní ìhòòhò láì fi nǹkan kan bora  Nígbà tí mo tún kọjá, tí mo rí ọ, mo rí i pé àsìkò àti nífẹ́ rẹ ti tó, mo fi iṣẹtí aṣọ mi bo ìhòòhò rẹ Mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ọ mo sì bá ọ dá májẹ̀mú láti di tèmi, ni Olúwa Ọlọ́run wí,  Nígbà náà ni mo fi omi wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ, mo fi ìpara pa ọ́ lára Mo fi aṣọ oníṣẹ́ ọ̀nà sí ọ lára láti wọ̀ ọ́, mo wọ bàtà aláwọ fún ọ Mo fi aṣọ funfun lẹlẹ àti aṣọ olówó iyebíye ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ Mo fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà ọwọ́ sí ọ lọ́wọ́, mo fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn sí ọ lọ́rùn, Mo sì tún fi òrùka sí ọ nímú, mo fi yẹtí sí ọ létí, mo sì fi adé tó rẹwà dé ọ lórí Báyìí ni mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà tí aṣọ rẹ jẹ́ funfun lẹlẹ, olówó iyebíye àti aṣọ tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí Ìyẹ̀fun kíkúnná, oyin àti òróró ni oúnjẹ rẹ O di arẹwà títí o fi dé ipò ayaba Òkìkí rẹ sì kàn káàkiri orílẹ̀ èdè nítorí ẹwà rẹ, nítorí dídán tí mo fi ṣe ẹwà rẹ láṣe pé, ni Olúwa Ọlọ́run wí  Ṣùgbọ́n, o gbẹ́kẹ̀lé ẹwà rẹ, o sì di alágbérè nítorí òkìkí rẹ O sì fọ́n oju rere rẹ káàkiri sórí ẹni yòówù tó ń kọjá lọ, ẹwà rẹ sì di tìrẹ O mú lára àwọn aṣọ rẹ, láti rán aṣọ aláràbarà fún ibi giga òrìṣà tí o ti ń ṣàgbèrè Èyí kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, tàbí kó tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá O tún mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ dáradára tí mo fi wúrà àti fàdákà ṣe fún ọ láti fi yá ère ọkùnrin tí ó ń bá ọ ṣe àgbèrè papọ̀ O sì wọ ẹ̀wù oníṣẹ́ ọnà rẹ fún wọn, o sì tún gbé òróró àti tùràrí mi sílẹ̀ níwájú wọn O tún gbé oúnjẹ tí mo fún ọ-ìyẹ̀fún dáradára, òróró àti oyin-fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyìí, ni Olúwa Ọlọ́run wí  Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí o bí fún mi lo ti fi rúbọ bí oúnjẹ fún àwọn òrìṣà Ṣé ìwà àgbèrè rẹ kò ha tó bí Ẹ dú àwọn ọmọ mí lọ́rùn, o fà wọ́n fún ère gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun, Nínú gbogbo iṣẹ́ ìríra àti ìwà àgbérè rẹ, o kò rántí ìgbà èwe rẹ, nígbà tó o wà ní ìhòòhò, tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀ Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, Ègbé! Ègbé ni fún ọ Lẹ́yìn gbogbo ìwà búburú rẹ, O kọ́lé amọ̀ fún ara rẹ, o sì kọ́ ojúbọ gíga sí gbogbo òpin oju pópó Ní gbogbo òpin ojú pópó lo kọ ojúbọ gíga sí tó o sì fi ẹwà rẹ̀ wọlé, o sọ àgbèrè rẹ di púpọ̀ nípa fífi ara rẹ sílẹ̀ fún gbogbo ẹni tó ń kọjá lọ O ṣe àgbèrè pẹ̀lú ará Éjíbítì tí í ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ aládúgbò rẹ láti mú mi bínú pẹ̀lú ìwà àgbèrè rẹ tó ń pọ̀ sí i Nítorí náà ni mo fi na ọwọ mi lòdì sí ọ, mo ge ilé rẹ kúrú èmi yóò sì mú ìfẹ́ àwọn to korìíra rẹ ṣẹ́ lé ọ lórí, àwọn ọmọbìnrin Fílístínì ti ìwàkiwà rẹ̀ jẹ ìyàlẹ́nu fún, Nítorí àìnítẹ́lọ́rùn rẹ o ṣàgbérè pẹ̀lú ara Ásíríà síbẹ̀ náà, o kò tún ní ìtẹ́lọ́rùn Ìwà àgbèrè rẹ tún tẹ̀ṣíwájú dé ilẹ̀ oniṣòwò ni Bábílónì síbẹ̀ náà, o kò tún ni ìtẹ́lọ́rùn Olúwa Ọlọ́run wí pé, Báwo ni ọkàn rẹ ṣe jẹ aláìlera tó tí o n ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àwọn agídí alágbérè! Nígbà tí o kọ́lé funra rẹ, tóo sì tún kọ ojúbọ gíga si gbogbo òpin ojú pópó síbẹ̀, o ko tún ṣe bi àwọn alágbèrè gidi nítorí pé o kọ̀ láti gbowó  Ìwọ alágbèrè aya! Ìwọ fẹ́ràn ọkùnrin àjèjì ju ọkọ rẹ lọ! Àwọn ọkùnrin máa ń sanwó fún àwọn aṣẹwó ni ṣùgbọ́n ìwọ lo tún ń sanwó fun wọn, tí ó tún ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn àti owó ẹ̀yìn kí wọn bá à le máa wá ọ wá láti gbogbo agbègbè fún àgbèrè ṣíṣe Nínú àgbèrè rẹ ìwọ yàtọ̀ sí àwọn alágbèrè obìnrin yòókù kò sí ẹni tó ń wá ọ fún àgbèrè Ìwọ ló ń sánwó nígbà tí wọn yóò sanwó fún ọ, ìdákejì ni ọ́ nítorí pé ìwọ ló ń sanwo bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò rí gbà  Nítorí náà, ìwọ alágbèrè, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ! Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Nítorí pé ìwọ tú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ jáde, ìwọ sì fi ìhòòhò rẹ hàn, nípa ṣíṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn olólùfẹ̀ẹ̀ rẹ, àti nítorí gbogbo ère tí o fi ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ṣe ìrúbọ fún, nítorí náà, Èmi yóò ṣa gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ jọ, pẹ̀lú gbogbo àwọn ti ẹ jọ ṣe fàájì, àwọn tí ìwọ fẹ́ àti àwọn tí ìwọ korìíra Èmi yóò ṣa gbogbo wọn káàkiri, láti mú wọn lòdì sí ọ, èmi yóò sí aṣọ rẹ, níwájú wọn, wọn yóò sì rí ìhòòhò rẹ Èmi yóò dá ọ lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti dá obìnrin tó ba ìgbeyàwó jẹ́, tí wọn sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ Èmi yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ ìbínú àti owú mi wá sórí rẹ Nígbà náà ni èmi yóò fà ọ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọ́wọ́, wọn yóò sì wó gbogbo òkìtì rẹ pẹ̀lú àwọn ojúbọ rẹ palẹ̀ Wọn yóò tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ ni wọn yóò gbà, wọn yóò sì fi ọ sílẹ̀ ní ìhòòhò àti ààbò Wọn yóò pe àjọ ènìyàn jọ lé ọ lórí, àwọn tí yóò sọ ọ́ ní òkúta, ti wọn yóò sì fi idà wọn gé ọ sí wẹ́wẹ́ Wọn yóò jo gbogbo ilé rẹ palẹ̀ wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ́ ní ojú àwọn obìnrin Èmi yóò fi òpin sí àgbèrè ṣíṣe rẹ Ìwọ kò sì ní san owó fún àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ́ Nígbà náà ni ìbínú mi sí Ọ yóò rọ̀, owú ìbínú mi yóò sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ inú mi yóò rọ, èmi kò sì ní bínú mọ́  Nítorí pé o kò rántí ọjọ́ èwe rẹ ṣùgbọ́n ìwọ ń rí mi fín pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ó dájú pé Èmi yóò mú gbogbo ohun tí ìwọ ti ṣe wa sórí rẹ, ni Olúwa Ọlọ́run wí, Ìwọ kì yóò sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí ni orí gbogbo ohun ìríra rẹ  Gbogbo àwọn to ń pòwe, ni yóò máa pòwe yìí mọ́ ọ pé Bí ìyá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ni ọmọ rẹ̀ obìnrin Ọmọ ìyà rẹ ni ọ lóòtọ́, to korìíra ọkọ rẹ àti àwọn ọmọ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ara ilé àwọn arábìnrin rẹ ni ọ nitootọ, àwọn to n korìíra ọkọ wọn sílẹ̀, tó tún ń korìíra àwọn ọmọ Ará Híítì ni ìyá rẹ, baba rẹ si jẹ́ ara Ámórì Ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin ni Samaríà, òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ n gbé ni apá aríwá rẹ, Sódómù sì ni àbúrò rẹ, obìnrin tó ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ ni ìhà gúúsù rẹ Kì í sẹ pé ìwọ rìn ni ọ̀nà wọn nìkan, tàbí ṣe àfiwé ìwà irira wọn ṣùgbọ́n ní àárin àkókò kúkúrú díẹ̀, ìwọ bàjẹ́ jù wọ́n lọ Olúwa Ọlọ́run wí pé, Bí mo ṣe wà láàyè Sódómù tí í se ẹgbọ́n rẹ obìnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ kò ṣe to ohun tí ìwọ àti ọmọbìnrin rẹ ṣe  Wò ó, ẹ̀sẹ̀ tí Sódómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin sẹ̀ nìyìí Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ gbéraga, wọ́n jẹ́ alájẹjù àti aláìbìkítà wọn kò ran talákà àti aláìní lọ́wọ́ Nítorí náà, mo mu wọn kúrò níwájú mi lójú mi gẹ́gẹ́ bi iwọ ti ròó, nítorí ìgbéraga àti àwọn Ohun ìríra tí wọ́n ṣe Samaríà kò ṣe ìdájìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ Ìwọ ṣe àwọn ohun ìríra ju tirẹ̀ lọ, ìwọ sì jẹ kí àwọn arabìnrin rẹ dàbí olódodo pẹ̀lú gbogbo ìwọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe Gba ìtìjú rẹ, nítorí ìwọ ti jẹ́ kí arábìnrin rẹ gba ìdáláre Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti burú ju tí wọn lọ, wọn dàbí olódodo ju ìwọ lọ Torí náà rú ìtíjú rẹ, kí o sì gba ẹ̀gàn rẹ pẹ̀lú nítorí ìwọ ti jẹ́ kí àwọn arábìnrin rẹ dàbí olódodo  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sódómù àti àwọn ọmọbìnrin rẹ padà ìgbèkùn àti Samaríà pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ, èmi yóò sì dá ìgbèkùn tirẹ̀ náà padà pẹ̀lú wọn Kí ó bá à le rú ìtìjú rẹ, àti ẹ̀gàn gbogbo ohun tí ìwọ se láti tù wọ́n nínú Nígbà tí àwọn arábìnrin rẹ, Sódómù àti àwọn ọmọbìnrin rẹ Samaríà àti àwọn ọmọbìnrin rẹ ba padà si ipò tí wọn wà tẹ́lẹ̀, ìgbà náà ni ìwọ náà yóò padà sí ipò àtijọ́ rẹ Iwọ ko tilẹ̀ ní dárúkọ arábìnrin rẹ Sódómù ni ọjọ́ ìgbéraga rẹ, Kó tó di pé àsírí ìwà búburú rẹ tú síta, báyìí ìwọ di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Édómù Síríà àti gbogbo agbègbè rẹ àti lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Fílístínì àti lọ́dọ̀ àwọn tó yí ọ ká, ti wọn si ń kẹ́gàn rẹ Èmi yóò gba ẹ̀san ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti àwọn iṣẹ́ ìríra rẹ ní Olúwa wí Báyìí ni Olúwa wí, Èmi yóò hùwà sí ọ gẹ́gẹ́ bi ó ṣe tọ́ sí ọ, nítorí o ti kẹ́gàn ẹ̀jẹ́ nípa dídà májẹ̀mú Síbẹ̀ èmi yóò rántí májẹ̀mú tí mo bá ọ ṣe nígbà ewe rẹ, èmi yóò sì bá ọ dá májẹ̀mú láéláé Nígbà náà ni ìwọ yóò rántí àwọn ọ̀nà rẹ ojú yóò sì tì ọ́ nígbà tí mo bá gba àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ obìnrin padà Fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin, ṣùgbọ́n kì í ṣe lórí májẹ̀mú tí mo bá ọ dá Èmi yóò gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì mọ pé èmi ni Olúwa Nígbà tí mo bá sì ti ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tan, Èmi yóò sì rántí ojú yóò tì ọ́, ìwọ kò sì ní le ya ẹnu rẹ mọ́ nítorí ìtìjú rẹ, ni Olúwa Ọlọ́run wí   Ẹyẹ Idì Méjì Àti Àjàrà Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ní wá wí pé Ọmọ ènìyàn pa àlọ́ kan, sì pa òwe kan fún ilé Ísírẹ́lì Sọ fún wọn pé, Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ orísìírísìí wa si Lẹ́bánónì o sì mu ẹ̀ka igi Kédàrì tó ga jùlọ O gé ọ̀mùnú orí ẹ̀ka yìí kúrò, o mu un lọ sí ilẹ̀ oníṣòwò, ó sì gbìn ín sí ìlú àwọn ọlọ́jà  Ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, ó gbìn ín bí igi wílóò Ó dàgbà, ó sì di àjàrà to kúrú ṣùgbọ́n to bolẹ̀ Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kọjú si i, gbòǹgbò rẹ̀ sì dúró lábẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o di àjàrà ó sì mu ẹ̀ka àti ewe jáde  Ṣùgbọ́n ẹyẹ Idì ńlá mìíràn tún wá, tó ní apá títóbi pẹ̀lú ìyẹ́ púpọ̀ Gbòǹgbò àjàrà náà sì ta lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti orí ilẹ̀ tí wọn gbìn ín sí, ó wá pẹ̀ka lọ sọ́dọ̀ rẹ kí ó le fún-un ni omi Orí ilẹ̀ tó dára lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ni a gbìn ín sí, kí ó bá à le pẹ̀ka, kò sí so èso, ó sì wá di igi àjàrà tó lọ́lá púpọ̀ Sọ fún wọn pé, Ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí nìyí Yóò wá gbilẹ̀ bí A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀ Kò sì ní gba agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòngbò rẹ̀ tu Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí Kò wá ní i rọ pátapáta nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà oòrùn bá kọ lù ú Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà   Nígbà náà, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá pé Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí, Ǹjẹ́ ẹ mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí Sọ fún wọn Ọba a Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kó Ọba àti àwọn ìjòyè ọmọ aládé ibẹ̀ lọ sí Bábílónì lọ́dọ̀ rẹ̀ Lẹ́yìn èyí ó bá ọ̀kan nínú ọmọ Ọba dá májẹ̀mú, ó mú un jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìbúra ó tún kó àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà Kí ìjọba ilẹ náà le re lẹ̀, láì ní le gbérí mọ́, àyàfi tí ó bá pa májẹ̀mú rẹ mọ ni yóò tó ó lè dúró Ṣùgbọ́n Ọba ṣọ̀tẹ̀ sí i nípa ríran aṣojú lọ sí Éjíbítì, kí wọn bá à lè fún-un ni ẹsin àti àwọn ọmọ ogun púpọ̀ Yóò ha ṣe àṣeyorí Ṣe ẹni tó ṣe irú nǹkan yìí yóò sì bọ́ níbẹ̀ Yóò wá da májẹ̀mú kó sì bọ́ níbẹ̀ bí  Bí mo ti wà láàyè ni Olúwa Ọlọ́run wí, níbi tí Ọba tó fi sórí oyè wà, ẹ̀jẹ́ ẹni tí ó kẹ́gàn àti májẹ̀mú ẹni tí ó dà, níbẹ̀ ni àárin Bábílónì ní yóò kùú sí Nígbà tí wọ́n bá pa bùdó ogun tì í, tí wọ́n sì mọ odi láti pa ọ̀pọ̀ ènìyàn, Fáráò pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àti àjọ ńlá rẹ̀ kò ní lè ṣe ìrànwọ́ fún-un lójú ogun Nítorí pé ó kẹ́gàn ẹ̀jẹ́ nípa dída májẹ̀mú, àti pé ó juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ìlérí, kò ní i bọ níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan to ṣe yìí  Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run wí pé Bí mo ti wà láàyè, Èmi yóò mú ẹ̀san ẹ̀jẹ́ mi tó kẹ́gàn àti májẹ̀mú mi tó dà wa sórí rẹ̀ Èmi yóò ta àwọ̀n mi sórí rẹ̀, yóò sì bọ sínú okùn mi, N ó mú ọ lọ Bábílónì láti ṣe ìdájọ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó hù sí mi Gbogbo ìsáǹsá àti ọ̀wọ́ ọmọ ogun rẹ̀ ni yóò kú pẹ̀lú idà, èmi yóò sì fọn àwọn ìyókù ká sínú afẹ́fẹ́ káàkiri Nígbà náà ni yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa lo sọ̀rọ̀  Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí Èmi fúnra mi yóò mú ọ̀kan lára ẹ̀ka tí ó ga jùlọ lori igi Kédàrí gíga, tí èmi yóò sì gbìn ín, èmi yóò sì gé ọ̀mùnú tí ó sẹ̀sẹ̀ yọ láti òkè, èmi yóò sì gbìn ín sórí òkè tó ga tó sì lókìkí Ní ibi gíga òkè Ísírẹ́lì ni èmi yóò gbìn ín sí yóò pẹ̀ka, yóò sì so èso yóò wa di igi Kédárì tí ó lọ́lá Orírsìírísìí ẹyẹ yóò sì fi òjìji abẹ ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé wọn yóò ṣe ibùgbé si abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀ Gbogbo igi inú oko yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ni ó mú igi gíga walẹ̀, tí mo sì mú kúkurú ga sókè, tí mo mu igi tútù gbẹ, tí mo sì mú igi gbígbẹ rúwé  Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀, Èmi yóò sì se e   Ọkàn Tí Ó Bá Ṣẹ̀ Ni Yóò Kú Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé Kín ni ẹ̀yín rò tí ẹ̀yin fi ń pa òwe nípa Ísírẹ́lì wí pé  Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà kíkan, eyín àwọn ọmọ sì kan Bí mo ti wà láàyè ni Olúwa Ọlọ́run wí, ẹ̀yin kó ni i pa òwe yìí mọ́ ni Ísírẹ́lì Nítorí pé èmi ló ní gbogbo ọkàn, ọkàn baba tèmi bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ pàápá jẹ tèmi, ọkàn tó bá sẹ̀ ní yóò kú Bí ọkùnrin Olódodo kan bá wà, tó ń ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ tí kò bá wọn jẹun lórí òkè gíga, tí kò gbójú rẹ̀ sókè sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ti kò sì bá obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ tàbí kí ó sùn ti obìnrin ni àsìkò èérí rẹ̀ Kò ní ẹnikẹ́ni lára, ó sì sanwó fún onígbésè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ìlérí fún un, kò fi ipá jalè ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì fi ẹ̀wù wọ àwọn tí ó wà ní ìhòòhò Kò yá ènìyàn ni owó ẹ̀dá tàbí kò gba èlé tó pọ̀jù Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ àìṣègbè láàrin ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀ Tí ó ń tẹ̀lé àsẹ mi, tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lotítọ́ àti lódodo Ó jẹ́ olódodo, yóò yè nítòótọ́, ní Olúwa Ọlọ́run wí Bí ó bá bi ọmọkùnrin, oniwà ipá, tó ń jalè, tó tún ń pànìyàn tó sì ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí sí arákùnrin rẹ̀ Ó ń jẹun lojúbọ lórí òkè gíga, o ba ìyàwó aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ Ó ni àwọn talákà àti aláìní lára, ó ń fipá jalè, kì í dá padà gẹ́gẹ́ bí ìlérí, o gbójú sókè sí òrìṣà, ó sì ń ṣe ohun ìríra Ó ń fowó ya ni pẹ̀lú èlé ó sì tún ń gba èlé tó pọ̀jù Ǹjẹ́ irú ọkunrin yìí wa le è yè bí Kò lè wá láàyè! Nítorí pé ó ti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, yóò kú, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wá lórí rẹ̀ Bí ọkùnrin yìí bá bímọ, tó sì rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti baba rẹ ń ṣẹ̀ yìí, tó sì bẹ̀rù, ti kò ṣe bẹ́ẹ̀ Tí kò jẹun lójúbọ lórí òkè gíga tàbí kò gbójú sókè sí àwọn òrìṣà ilé Ísírẹ́lì, tí kò sì bá iyàwó aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ tí kò ni ẹnikẹ́ni lára, tí kò hùwà ibi tí kò gba èlé tàbí kò fipá jalè ṣùgbọ́n tí ó ń fún ẹni tébi ń pa lóúnjẹ, tó sì fi aṣọ bo àwọn oníhòhò Ó ń yọ ọwọ́ rẹ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, kò sì gba èlé tàbí èlé tó pọ̀jù, ó ń pa òfin mi mọ́, ó sì ń tẹ̀lé àwọn àsẹ mi Kò ní kú fún ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, nítòótọ́ ní yóò yè! Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ arẹ́nijẹ, ó jalè arákùnrin rẹ, ó ṣe ohun tí kò dára láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ Síbẹ̀, ẹ tún ń bèèrè pé, Kí ló dé ti ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ, tó sì ti kíyè sí ara láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, nítòótọ́ ni pé yóò yè Ọkàn tí ó bá sẹ̀ ní yóò kú Ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni baba náà kò ní i ru ẹ̀bi ọmọ rẹ̀ Ìwà rere ènìyàn rere yóò wà lórí rẹ̀, ìwà búburú ti ènìyàn búburu náà la ó kà síi lọ́rùn Ṣùgbọ́n bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó ti dá, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àsẹ mi mọ́, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, nítòótọ́ ni yóò yè, kò sì ní kú A kò sì ní rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó ti dá tẹ́lẹ̀ láti kàá sí lọ́rùn nítorí tí ìwà òdodo rẹ tó fihàn, yóò yè Ǹjẹ́ se mo ni inú dídùn si ikú ènìyàn búburú bí í Ní Olúwa wí, dípò èyí inú mi kò ha ni i dùn nígbà tó ba yípadà kúrò ni àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ tó sì yè Ṣùgbọ́n bí ènìyàn rere bá yípadà kúrò ni ọ̀nà òdodo rẹ̀ tó sì ń dẹ́sẹ̀, tó sì tún n ṣe àwọn ohun ìríra tí ènìyàn búburú ń ṣe, yóò wa yè bí A kò ni i rántí ọ̀kan kan nínú ìwà rere rẹ̀ mọ́, nítorí ó ti jẹ̀bi ìwà àrékérekè àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì kú Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ tún sọ pe, Olúwa kò ṣe é da kò tọ́ Gbọ́, ilé Ísírẹ́lì se ọ̀nà mi ni kò tọ́ Kì í wa ṣé pé ọ̀nà ti yín gan-an ni kò tọ́ Bí ènìyàn rere ba yípadà kúrò nínú ìwà rere rẹ̀, tó sì dẹ́sẹ̀, yóò ku fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóò kú nítorí ẹsẹ tó ti dá Ṣùgbọ́n bi ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú tó ti se, tó si ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, yóò gba ẹ̀mi rẹ̀ là Nítorí pé ó ronu lórí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá, ó sì yípadà kúrò nínú wọn, nítootọ́ ni yóò yè kò sí ní i kú Síbẹ̀, ilé Ísírẹ́lì wí pé, Ọ̀nà Olúwa kò tọ́ Ọ̀nà mi kò ha tọ́ bí Ilé Ísírẹ́lì Kì í wa se pè ọ̀nà tiyín gan an ni ko tọ Nítorí náà, ilé Ísírẹ́lì, n ó da yín lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ẹnì kọ̀ọ̀kan yín bá ṣe rí ni Olúwa Ọlọ́run wí Yípadà! Kí ẹ si yí kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀ṣẹ̀ ma ba a jẹ́ ọ̀nà ìsubú yín Ẹ kọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti ẹ ti dá sílẹ̀, kí ẹ sì gba ọkàn àti ẹ̀mi tuntun Nitori kí ló fi máa kú, ilé Ísírẹ́lì Nítorí pé inú mi kò dùn sí ikú ẹnikẹ́ni ni Olúwa Ọlọ́run wí Nítorí náà, ẹ yípadà kí ẹ sì yè! Orin Ọ̀fọ̀ Nítorí Àwọn Ọmọ Aládé Ísírẹ́lì Kọ orin ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ aládé Ísírẹ́lì wí pé  Èwo nínú abo kìnnìnu ni ìyá rẹ̀ ní àárin àwọn kìnnìún yóòkù Ó sùn ní àárin àwọn ọ̀dọ́ kìnnìún ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀ Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára, ó kọ́ ọ láti sọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ Àwọn orílẹ̀ èdè gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú ààfin wọn Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì  Nígbà tí abo kìnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì já sí asán, ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára Ó sì ń rìn káàkiri láàrin àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára, o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọ̀n ìlú wọn di ahoro Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀ Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀ èdè tó yìí ká dìde sí i, wọn ta ẹ̀wọ̀n fún un, wọn sì mú nínú ihò wọn Wọn fi ìkọ́ gbé e sínú ago, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba Bábílónì, wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Ísírẹ́lì  Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀ tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso, ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè, ó ga sókè láàrin ewé rẹ̀, gíga rẹ̀ hàn jáde láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀ Ṣùgbọ́n a hú àjàrà yìí pẹ̀lú ìbínú, á sì wo o lulẹ̀, afẹ́fẹ́ láti ìlà oorùn sì mú koko, wọ́n sọ ọ́ di aláìléso, àwọn ẹka rẹ̀ tó lágbára tẹ́lẹ̀ sì rọ wọ́n sì jó wọn Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀ ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pọ̀ǹgbẹ omi Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀ ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run, débi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́ èyí to ṣe e fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́ Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀ Ọlọ́run Pe Ísíkẹ́lì Ó sọ fún mi pé, Ọmọ ènìyàn, dìde dúró lórí ẹṣẹ̀ rẹ Èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ Bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀, ẹ̀mí sì wọ inú mi ó mú mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi, mo sì ń gbọ́ tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ Ó sọ pé, Ọmọ ènìyàn, mo ń rán ọ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, sí ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi àwọn àti baba ńlá wọn ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi títí di òní-olónìí Àwọn ènìyàn tí mo ń rán ọ sí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle Sọ fún wọn pé, Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí Bí wọn fẹ́tísílẹ̀ tàbí wọn kò fẹ́tísílẹ̀—nítorí pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n—wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan wà láàrin wọn Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn Má ṣe bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣùṣú àti ẹ̀gún yí ọ ká, tí o sì ń gbé àárin àwọn àkéekèé Má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń sọ tàbí bẹ̀rù wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ìdílé ni wọ́n Ìwọ gbọdọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, bí wọ́n gbọ́ bí wọn kọ̀ láti gbọ́ torí pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n Ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, gbọ́ ohun tí mo ń sọ fún ọ Má se ṣọ̀tẹ̀ bí i ti ìdílé ọlọ́tẹ̀ la ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí mo fún ọ Mo sì wò, mo sì rí ọwọ́ kan tí a nà sí mi Ìwé tí a ká sì wà níbẹ̀, ó sì tú ìwé náà fún mi Ní ojú àti ẹ̀yìn ìwé náà ni a kọ ohùnréré ẹkún, ọ̀fọ̀ àti ègún sí Ìwà Ọlọ́tẹ̀ Tí Ísírẹ́lì Hù Ní ọjọ kẹ́wàá, oṣù kàrùn-ún ọdún keje, ní díẹ̀ nínú àwọn àgbà Ísírẹ́lì wá wádìí lọ́wọ́ Olúwa , wọn jòkòó níwájú mi Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn àgbà Ísírẹ́lì, kì ó sì wí fún wọn pé, Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí Ṣe ki ẹ lè wádìí lọ́dọ̀ mi ni ẹ ṣe wá Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí N ò ní í gbà kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí Ìwọ fẹ dájọ́ wọn bí ọmọ ènìyàn Nítorí náà fi gbogbo ìwà ìríra baba wọn kò wọ́n lójú, kí ó sọ fún wọn pé Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí Ní ọjọ tí mo yàn Ísírẹ́lì, mo gbé ọwọ́ mi ṣokè nínú ẹ̀jẹ́ sí àwọn ọmọ ilé Jákọ́bù, mo sì fi ara mi hàn wọn ní Éjíbítì, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ẹ̀jẹ́ wí pé, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín Ní ọjọ́ náà mo lọ jẹ́jẹ̀ẹ́ fún wọn pé ń ó mú wọn kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn ilẹ̀ yòókù Mo sì sọ fún wọn pé, Kí ẹ̀ni kọ̀ọ̀kan yín mú àwọn àwòrán ìríra ti ẹ gbé ṣíwájú yín kúrò, kí ẹ sì má bára yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìsà Éjíbítì, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín  Ṣùgbọ́n wọn sọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́ràn, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojú kọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Éjíbítì sílẹ̀, torí náà mo sọ pé ń ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, ń ó sì jẹ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Éjíbítì Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè tí wọn ń gbé láàrin wọn, lójú àwọn ẹni tí mo ti fi ara hàn fún ara Ísírẹ́lì nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Éjíbítì Nítorí náà, mo mú wọn jáde ní ilẹ̀ Éjíbítì mo sì mú wọn wá sínú ihà Mo sì fún wọn ni òfin mi, mo sì fi àwọn òfin mi hàn wọ́n nítori pé ẹni tó bá ṣe wọ́n yóò yè nípa wọn Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí àmì láàrin àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa tó sọ wọn di mímọ́  Síbẹ̀ ilé Ísírẹ́lì sọ̀tẹ̀ sí mí nínú ihà Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀-bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè è nínú rẹ̀ Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ Nítorí náà, mo sọ pé ń ó tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, ń ó sì pa wọ́n run nínú ihà Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní mú kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè tí mo kó wọn jáde lójú wọn Nítorí náà, mo tún gbọ́wọ́ mi sókè jẹ́jẹ̀ẹ́ fún wọn nínú ihà pé ń kò ní i mú wọn dé ilẹ̀ tí mo fi fún wọn—ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn ilẹ̀ yòókù Nítorí pé wọn kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé àsẹ mi, wọn sọ ọjọ́ ìsinmi mi dí aláìmọ́ Nítorí pé tọkàntọkàn ni wọn ń tẹ̀lé òrìṣà wọn Síbẹ̀síbẹ̀ mo wò wọ́n pẹ̀lú àánú, ń kò sì pa wọ́n run tàbí kí òpin dé bá wọn nínú ihà Ṣùgbọ́n mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú ihà pé, Ẹ má ṣe rìn ní ìlànà àwọn baba yín tàbí kí ẹ pa òfin wọn mọ́ tàbí kí ẹ bara yín jẹ́ pẹ̀lú òrìṣà wọn Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ó sì pa òfin mi mọ́ Ẹ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́ kí ó lè jẹ́ àmì láàrin wa ki ẹ lè mọ̀ pé èmi ní Olúwa Ọlọ́run yín  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn kò sì pa òfin mí mọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá tẹ̀lé àwọn òfin yìí, yóò yè nínú rẹ̀, wọ́n sì tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ Nítorí náà, mo sọ pé ń ó tú ìbínú mi lórí wọn N ó sì mú kí ibínú gbígbóná mi wá sórí wọn ni ihà Síbẹ̀síbẹ̀ mo dáwọ́ dúró, nitori orúkọ mi mo sì ṣe ohun tí kò ní bá orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè ti mo kó wọn jáde lójú wọn Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú ọwọ ti mo gbé sókè, mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún wọn nínú ihà pé n ó tú wọn ka sì àárin àwọn orílẹ̀ èdè, ń ó sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ gbogbo, nítorí pé wọn kò pa òfin mí mọ́, wọn sì tún kọ àsẹ mi sílẹ̀, wọn tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ Ọkàn wọn sì dúró ṣinṣin sọ́dọ̀ òrìṣà baba wọn Èmi náà sì fi wọn fún ìlànà tí kò dára àti òfin tí wọn kò le e yè nípa rẹ̀ Mo jẹ́ kí ó sọ wọn di aláìmọ́ nípa ẹ̀bùn-nipa fífi àkọ́bí ọmọ wọn rú ẹbọ sísun àkọ́bí wọn la iná kọjá, kí ń lè kó ìpayà bá wọn, kí wọn le mọ̀ pé èmi ni Olúwa Nítorí náà ọmọ ènìyàn, sọ fún ilé Ísírẹ́lì kí ó sì wí fún wọn pé, Èyí ní ohun ti Olúwa Ọlọ́run wí Nínú èyí náà, baba yín ti sọ̀rọ̀ àìtọ́ sí mi nípa kíkọ mi sílẹ̀ Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ṣe ìlérí láti fún wọn, gbogbo igi ilẹ̀ gíga àti gbogbo igi to rúwé ni wọn tí ń rúbọ wọn ṣe irubọ to ń mú mi bínú, níbẹ̀ sì ni wọn ń ṣe òórùn dídùn wọn, ti wọn sì ń ta ọrẹ ohun mímu sílẹ̀ Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé Kí ní ibi gíga tí ẹ n lọ yìí   Nítorí náà sọ fún ile Ísírẹ́lì Èyí ní ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí Ṣe o fẹ bara rẹ jẹ́ bi àwọn baba rẹ ṣe ṣe, to ń ṣe àgbèrè nípa tí tẹ̀lé àwọn àwòrán ìríra Nígbà tí ẹ̀yin bá san ọrẹ yìí, irúbọ ọmọkùnrin ọmọ yín, tí ẹ mú wọn la iná kọjá-ẹ ń tèṣíwájú láti bára yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà yín títí di òní yìí, èmi ó wa jẹ ki ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi bí ilé Ísírẹ́lì Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, N kò ní i jẹ́ kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi  Ẹ̀yin wí pé, Àwa fẹ dàbí àwọn orílẹ̀ èdè yóòkù, bí àwọn ènìyàn ayé, tó ń bọ igi àti òkúta Ṣùgbọ́n ohun ti ẹ ni lọ́kàn kò ní ṣẹ rárá Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, ń ó jọba lórí yín pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí ń ó nà jáde pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná mi Èmi yóò mú yín jáde láàrin àwọn ènìyàn, èmi yóò sì ṣà yín jọ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí a fọ́n yín sí pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí èmi yóò nà jáde àti pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná ni Èmi yóò mú yín wá sí ihà àwọn orílẹ̀ èdè, níbẹ̀ ni ojúkójú ni èmi yóò ṣe ìdájọ́ lé e yín lórí Bí mo ṣe ṣe idájọ́ àwọn baba yín nínú ihà nílẹ̀ Éjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe idájọ́ yín ní Olúwa Ọlọ́run wí Èmi yóò kíyèsí i yín bí mo ti mú un yín kọjá lábẹ́ ọ̀pá, èmi yóò sì mú yín wá sí abẹ́ ìdè májẹ̀mú Èmi yóò ṣa àwọn tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí mí kúrò láàrin yín Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé èmi yóò mú wọn kúrò ní ilẹ̀ tí wọn ń gbé, síbẹ̀ wọn kò ní dé ilẹ̀ Ísírẹ́lì Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ní Olúwa  Ní tí ẹ̀yin, ilé Ísírẹ́lì, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí Kí olúkúlùkù yín lọ máa sìn òrìṣà rẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, ẹ̀yin yóò gbọ́ tèmi, ẹ̀yin kò sí ní i bá orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ọrẹ àti àwọn òrìṣà yín mọ́ Nítorí lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Ísírẹ́lì, ni Olúwa Ọlọ́run wí, níbẹ̀ ni ilẹ̀ náà ní gbogbo ilé Ísírẹ́lì yóò sìn mí n ó sì tẹ́wọ́ gba wọ́n níbẹ̀ Níbẹ̀ ń ó bèèrè ọrẹ àti ẹ̀bùn nínú àkọ́so yín pẹ̀lú gbogbo ẹbọ mímọ́ yín N o tẹ́wọ́ gbà yín gẹ́gẹ́ bí tùràrí olóórùn dídùn nígbà tí mo ba mú yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí a fọ́n yín ká sí, ń ó sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrin yín lójú àwọn orilẹ̀ èdè Nígbà náà ni ẹ o mọ̀ pé èmi ní Olúwa , nígbà tí mo bá mú yín wa sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì sí ilẹ̀ tí mo gbọ́wọ́ mí sókè nínú ẹ̀jẹ́ láti fún àwọn baba yín Níbẹ̀ ni ẹ ó wa rántí ìwà àti gbogbo ìsesí yín, èyí tí ẹ̀yin fi sọ ara yín di aláìmọ́, ẹ̀yin yóò sì kóríra ara yín fún gbogbo ibi tí ẹ̀yin ti se Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa , nígbà tí mo bá hùwà sí yín nítorí orúkọ mi ni, tí ń kò hùwà sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ibi àti ìwà ìríra yín Ẹ̀yin Ilé Ísírẹ́lì, ni Olúwa Ọlọ́run wí   Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, dojú kọ ìhà gúsù wàásù lòdì sí gúsù kí ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ sí igbó ilẹ̀ gúsù Sọ fún igbo ìhà gúsù Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Èyí ní ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí Kíyèsí í, èmi yóò dá iná kan nínú rẹ̀ yóò sì jó olúkúlùkù igi tutu nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù igi gbígbẹ Jíjí ọwọ́ iná náà kò ní i ṣe e pa, àti gbogbo ojú láti gúsù dé aríwá ni a ó sun nínú rẹ̀ Gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé Èmi Olúwa ni ó dá a, a kì yóò sì le è pa á   Nígbà náà ni mo wí pé, Áà! Olúwa Ọlọ́run! Wọn ń sọ fún mi pé, Kì í wa ṣe pé òwe lo ń pa bí   Bábílónì Ìdà Ọlọ́run Fún Ìdájọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ mi wá Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí ìhà Jérúsálẹ́mù, kí o sí wàásù lòdì sí ibi mímọ́ Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ilẹ Ísírẹ́lì Kí ó sì sọ fún un Èyí yìí ni Olúwa sọ Èmi lòdì sí ọ Èmi yóò fa idà mi yọ kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀, Èmi yóò sì ké olódodo àti ènìyàn búburú kúrò ni àárin yín Nítorí pé, èmi yóò ké olódodo àti olùṣe búburú kúrò, idà mi yóò jáde láti inú àkọ̀ rẹ̀ lòdì sí gbogbo ènìyàn láti gúsù títí dé àríwá Nígbà náà gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti yọ idà mi kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀ kì yóò sì padà sínú rẹ̀ mọ́ Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mi ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mi ìmí ẹ̀dùn Ìwọ yóò wí pé, Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ wí pé, Èyí yìí ní Olúwa wí  Ìdá kan, Ìdá kan, tí a pọ́n tí a sì kùn a ti pọ́n fún pípa, a sì dan an kí ó lè máa kọ bí mọ̀nàmọ́ná!  Àwa yóò ha si ọ̀pá aládé ọmọ mi Júdà Idà kẹ́gàn gbogbo ọ̀pá  Idà ní a yàn láti pọ́n, kí ó lè ṣe é gbá mú a pọ́n ọn a sì dan án, ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani Sunkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn, nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi yóò wá sórí gbogbo ọmọ aládé Ísírẹ́lì ìbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi nítorí idà náà nítorí náà lu oókan àyà rẹ  Ìdánwò yóò dé dandan Tí ọ̀pá aládé Júdà èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ ṣíwájú mọ́ ńkọ́ Ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ kí ó sì fí ọwọ́ lu ọwọ́ Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì, kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta Ó jẹ́ idà fún ìpànìyàn idà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀ Tí yóò sé wọn mọ́ níhìnín àti lọ́hùnnún Kí ọkàn kí ó lè yọ́ kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀, mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun Áà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná, a gbá a mú fún ìparun Ìwọ idà, jà sí ọ̀tún kí o sì jà sí òsì lọ ibikíbi tí ẹnu rẹ bá dojúkọ Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́ ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀ Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀ Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mi wá Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fín idà ọba Bábílónì láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà Ṣe àmì sí ìkòríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọ lu Rábà ti àwọn ará Ámónì kí òmíràn kọ lu Júdà, kí ó sì kọ lu Jérúsálẹ́mù ìlú olódi Nítorí ọba Bábílónì yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti wá àmìn nǹkan tí ń bọ̀ Yóò fi ọfà di ìbò, yóò bèèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀ Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jérúsálẹ́mù yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́ Yóò dàbí àmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn Nítorí náà èyíí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀sẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbékùn  Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ aládé Ísírẹ́lì, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góngó, Èyí yìí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀ Ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀, Ìparun! Ìparun! Èmi yóò sé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò se pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in òun ni èmi yóò fifún Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọ̀tẹ̀lẹ kí ó sì wí pé, Èyí yìí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí nípa àwọn ará Ámónì àti àbùkù wọn  Idà kan idà kan tí á fa yọ fún ìpànìyàn tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná! Bí ó tilẹ jẹ́ pé a rì èké nípa yín àti àfọ̀sẹ èké nípa yín a yóò gbé e lé àwọn ọrùn ènìyàn búburú ti a yóò pa, àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé, àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó Dá idà padà sínú akọ rẹ̀ Níbi tí a gbé sẹ̀dá yín, ní ibi tí ẹ̀yin ti sẹ̀ wá Níbẹ̀ ni èmi yóò ti ṣe ìdájọ́ yín, èmi yóò sì fi èémí ìbínú gbígbóná mi bá yín jà Ẹ̀yin yóò jẹ́ èpò fún iná náà, a yóò ta ẹ̀jẹ̀ yin sórí ilẹ̀ yín, a ki yóò rántí yín mọ́ nitorí èmi Olúwa ní ó ti wí bẹ́ẹ̀   Àwọn Ẹ̀sẹ̀ Jérúsálẹ́mù Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn ǹjẹ́ ìwọ yóò ha ṣe ìdájọ́ rẹ̀ Ǹjẹ́ ìwọ ha ṣe ìdájọ́ ìlú atàjẹ̀sílẹ̀ Tó bá rí bẹ́ẹ̀ dojúkọ wọn pẹ̀lú gbogbo ìwà ìríra wọn Kí ó sì wí pé Èyí yìí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ìwọ ìlú ńlá tí ó mú ìparun wá sórí ara rẹ nípa títàjẹ̀sílẹ̀ ní àárin rẹ, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa ṣíṣe àwọn ère, Ìwọ ti jẹ̀bi nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀, àti pé àwọn ère tí ó ṣe tí bà ọ́ jẹ́ Ìwọ tí mú ọjọ́ rẹ súnmọ́ tòsí, iparí àwọn ọdún rẹ sì ti dé Nítorí náà èmi yóò fi ọ ṣe ohun ẹ̀gàn lójú àwọn orílẹ̀ èdè àti ohun ẹ̀sín lójú gbogbo ìlú Àwọn tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó jìnnà, yóò fi ọ se ẹlẹ́yà, Áà! ìwọ ìlú ẹlẹ́gàn, tí ó kún fún làálàá  Wo bí ìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Ọba Ísírẹ́lì tí ó wà nínú yín ti ń lo agbára rẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀ Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwà-kúwà sí aláìní baba àti opó Ìwọ tí kọ àwọn ohun mímọ́ mi sílẹ̀, ìwọ sì ti lo ọjọ́ ìsinmi mi ní ìlòkúlò Nínú rẹ ni àwọn ayanijẹ ènìyàn pinnu láti tàjẹ̀ sílẹ̀ nínú rẹ ní àwọn tí ó ń jẹun ní orí òkè ojúbọ òrìṣà, wọn sì hùwà ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ Nínú rẹ ní àwọn ti kò bu ọla fún àwọn àkéte baba wọn nínú rẹ ni àwọn ti o ń bá àwọn obìnrin lò nígbà tí wọ́n ń ṣe àkókò lọ́wọ́, ní àsìkò tí a ka wọn sì aláìmọ́ Nínú rẹ ọkùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìríra pẹ̀lú aya aládùúgbò rẹ̀, òmíràn bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ ṣe, òmíràn sì bá arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ èyí tí í ṣe ọbàkan rẹ̀ Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀ Ìwọ gba èlé lọ́pọ̀pọpọ̀ láti mú aláìsòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ Ìwọ sì ti gbàgbé ẹ̀ mi ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí  Èmi yóò kúkú pàtẹ́wọ́ lórí èrè àìmọ̀ tí ìwọ ti jẹ, àti lórí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀ ní àárin yín Ǹjẹ́ ìwọ yóò lè ní ìgboyà tó, tàbí ọwọ́ rẹ yóò ni agbára ní ọjọ́ tí èmi yóò ni ṣíṣe pẹ̀lú rẹ Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, Èmi yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ Èmi yóò tú kán ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò fọ́n ọ ká sí àwọn ìlú èmi yóò sì fi òpin sí àìmọ́ rẹ Nígbà tí a ó bà ọ́ jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè, ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa   Nígbà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, ilé Ísírẹ́lì ti di ìdárọ́ sí mi gbogbo wọn jẹ́ bàbà, tánúnganran, ìrin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Nítorí tí ìwọ ti di ìdárọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jérúsálẹ́mù Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti tánúnganran jọ sínú iná ìléru láti fi amúbí ina yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunnú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárin ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́ Èmi o ko yín jọ, èmi o sì fín iná ibínú mi si yin lára, ẹ o si di yíyọ́ láàrin rẹ̀ Bí a ti ń yọ́ fàdákà nínú iná ìléru bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ìwọ yóò se yọ́ nínú rẹ̀, ìwọ yóò sì mọ̀ wí pé èmi Olúwa ti tú ìbínú mi sórí rẹ   Lẹ́ẹ̀kan síi ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé, Ọmọ ènìyàn, sọ fún ilẹ̀ náà, Ìwọ ní ilẹ̀ tí kò ti ní rọ òjò tàbí ìrì ní àkókò ìbínú Ìdìtẹ̀ sì wà láàrin àwọn ọmọ aládé inú rẹ̀, tó dàbí bíbú kìnnìún tó ń fà ẹ̀ran ya, wọ́n ń ba àwọn ènìyàn jẹ́, wọ́n ń kó ìsúra àti àwọn ohun iyebíye wọ́n sì ń sọ púpọ̀ di opó nínú rẹ̀ Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti rú ofin mi, wọn si ti sọ ohun mímọ́ mi di àìlọ́wọ̀ wọn kò fi ìyàtọ̀ sáàrin ohun mímọ́ àti àìlọ́wọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi ìyàtọ̀ hàn láàrin ohun àìmọ́, àti mímọ́, wọn sì ti fi ojú wọn pamọ́ kúrò ní ọjọ ìsinmi mi, mó sì dí ẹni àìlọ́wọ̀ láàrin wọn Àwọn ọmọ aládé àárin rẹ̀ dàbí ikokò ti ń ṣọ̀tẹ̀, láti tàjẹ̀ sílẹ̀, láti pa ọkàn run, láti jèrè àìsòótọ́ Àti àwọn wòlíì rẹ̀ ti ṣẹ̀tàn sí wọn, wọn ń rì iran asán, wọn sì ń fọ àfọ̀sẹ èké sí wọn, wí pé, Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí, nígbà tí ó ṣépè Olúwa kò sọ̀rọ̀ Àwọn enìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìnínilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídí Kò sì sí ìdájọ́ òdodó Èmi si wá ẹnìkan láàrin wọn, tí ìbá tún odi náà mọ́, tí ìbá dúró ní ibi tí ó ya náà níwájú mi fún ilẹ̀ náà, kí èmi má báà parun ṣùgbọ́n èmi kò rí ẹnìkan Nítorí náà ni mo ṣe ma da ìbínú mi sí wọn lórí máa fí iná ìbínú mi run wọn mo si ma fi ọ̀nà wọn gbẹ̀san lórí ara wọn, ní Olúwa Ọlọ́run wí Obìnrin Tẹ̀gbọ́n Tàbúrò Aṣẹ́wó Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, obìnrin méjì wà, ọmọ ìyá kan náà Wọn ń ṣe panṣágà ní Éjíbítì, wọn ń ṣe panṣaga láti ìgbà èwe wọn Ní ilẹ̀ yẹn ni wọn ti fi ọwọ́ pa ọyàn wọn, níbẹ̀ ni wọn sì fọwọ́ pa igbá àyà èwe wọn Èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Óhólà, àbúrò rẹ̀ sì ń jẹ́ Óhólíbà Tèmí ni wọn, wọ́n sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Óhólà ni Samaríà, Óhólíbà sì ni Jérúsálẹ́mù Óhólà ń ṣe asẹ́wó nígbà tí ó sì jẹ́ tèmi Ó sì ṣe ìfẹ́kúfẹ́ sí àwọn olólùfẹ̀ rẹ̀, àwọn jagunjagun ará Ásíríà Aṣọ aláró ni a fi wọ̀ wọ́n, àwọn gómìnà àti àwọn balógun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà àwọn tí ń gun ẹsin O fi ara rẹ̀ fún gbajúmọ̀ ọkùnrin Ásíríà gẹ́gẹ́ bí pansága obìnrin, o fi òrìsà gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, kò fi ìwa aṣẹ́wó tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ni Éjíbítì sílẹ̀, ní ìgbà èwe rẹ̀ àwọn ọkùnrin n bá a sùn, wọn fi ọwọ́ pa àyà èwe rẹ̀ lára wọn sì ń ṣe ìfẹ́kúùfẹ́ sí i Nítorí náà mo fi i sílẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ará Ásíríà, tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i Wọ́n bọ́ ọ sí ìhòòhò, wọ́n sì gba àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọn sì pá wọn pẹ̀lú idà Ó di ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ láàrin àwọn obìnrin wọ́n sì fi ìyà jẹ ẹ́ Àbúrò rẹ̀ Óhólíbà rí èyí, síbẹ̀ nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti aṣẹ́wó rẹ̀, Ó ba ara rẹ jẹ́ ju ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ Oun náà ní ìfẹ́kúùfẹ́ sí ará Ásíríà àwọn gómìnà àti àwọn balógun, jagunjagun nínú aṣọ ogun, àwọn tí ń gun ẹṣin, gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà Mo rí i pé òun náà ba ara rẹ̀ jẹ́ àwọn méjèèjì rìn ojú ọ̀nà kan náà Ṣùgbọ́n ó tẹ̀ ṣíwájú nínú ṣíṣe aṣẹ́wó O ri àwòrán àwọn ọkùnrin lára ògiri, àwòrán àwọn ara Kálídíà àwòrán púpa, pẹ̀lú ìgbànú ni ìdí wọn àti àwọn ìgbàrí ni orí wọn gbogbo wọn dàbí olórí kẹ̀kẹ́ ogun Bábílónì ọmọ ìlú Kálídíà Ní kété tí ó rí wọn, ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí wọn, ó sì rán onísẹ́ sí wọn ni Kálídíà Àwọn ará Bábílónì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, lórí ìbùsùn ìfẹ́, nínú ìfẹ́kúùfẹ́ wọn, wọ́n bà á jẹ́ Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn ní ìtìjú Nígbà tí ó tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ̀ ní gbangba wọ́n sì túu sí ìhòòhò, mo yí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ìtìjú, gẹ́gẹ́ bí mo ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Síbẹ̀síbẹ̀ ó ń pọ̀ síi nínú ìdàpọ̀ rẹ̀ bí ó ti ń rántí ìgbà èwe rẹ̀ tí ó jẹ́ asẹ́wó ní Éjíbítì Níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, tí àwọn tí ǹnkan ọkùnrin wọn dàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ẹni tí ìtíjáde ara wọn dàbí ti àwọn ẹṣin Ó ń fojúsọ́nà sí àìlófin ìgbà èwe rẹ̀ ni Éjíbítì, nìgbà tí wọ́n fi ọwọ́ pa igbáàyà rẹ̀ àti ọmú ìgbà èwe rẹ̀ Nítorí náà, Óhólíbà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí Èmi yóò gbé olólùfẹ́ rẹ dìde sí ọ, àwọn tí o kẹ́yìn si ní ìtìjú, èmi yóò sì mú wọn dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà àwọn ará Bábílónì àti gbogbo ara Kálídíà àwọn ọkùnrin Pékódùk àti Ṣóà àti Kóà àti gbogbo ará Ásíríà pẹ̀lú wọn, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà, gbogbo àwọn gómìnà àti balógun, olórí oníkẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn onípò gíga, gbogbo àwọn tí ń gun ẹṣin Wọn yóò wa dojú kọ ọ pẹ̀lú ohun ìjà, kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹrù àti pẹ̀lú ìwọ́jọpọ̀ ènìyàn wọn yóò mú ìdúró wọn lòdì sí ọ ní gbogbo ọ̀nà pẹ̀lú àṣà ńlá àti kékeré pẹ̀lú àsíborí Èmi yóò yí ọ padà sí wọn fun ìjìyà, wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ gẹ́gẹ́ bí wọn tí tó Èmi yóò sì dojú ìbínú owú mi kọ ọ́, wọn yóò sì fìyà jẹ ọ́ ní ìrunnú Wọ́n yóò gé àwọn imú àti àwọn ètí yín kúrò, àwọn tí ó kù nínú yín yóò ti ipá idà ṣubú Wọn yóò mú àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin yín lọ, àwọn tí o kù nínú yín ni iná yóò jó run Wọn yóò sì kó àwọn aṣọ àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye yín Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti iṣẹ́ aṣẹ́wó tí ẹ bẹ̀rẹ̀ ni Éjíbítì Ẹ̀yin kò ní wo àwọn nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú aáyun, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rántí Éjíbítì mọ Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí Èmi yóò fi ọ lé ọwọ́ àwọn tí ó korìíra, lọ́wọ́ àwọn ẹni tí ọkàn rẹ ti sí kúrò Wọn yóò fìyà jẹ ọ́ pẹ̀lú ìkórìíra, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tí o ṣiṣẹ́ fún lọ Wọn yóò fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò goloto, ìtìjú iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ ni yóò farahàn Ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti ìdàrúdàpọ̀ rẹ ni ó mú èyí wá sórí rẹ, nítorí tí ìwọ ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si orílẹ̀ èdè, o sì fi àwọn òrìṣà rẹ́ ara rẹ jẹ Ìwọ ti rin ọ̀nà ti ẹ̀gbọ́n rẹ rìn Èmi yóò sì fi aago rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́ Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè Ìwọ yóò mu nínú aago ẹ̀gbọ́n rẹ, aago tí ó tóbi tí ó sì jinnú yóò mú ìfisẹ̀sín àti ìfiṣe ẹlẹ́yà wá, nítorí tí aago náà gba nǹkan púpọ̀ Ìwọ yóò mu àmupara àti ìbànújẹ́, aago ìparun àti ìsọdahoro aago ẹ̀gbọ́n rẹ Samaríà Ìwọ yóò mú un, ni àmugbẹ ìwọ yóò sì fọ sí wẹ́wẹ́ ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ̀ ya Èmi ti sọ̀rọ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí Nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí Níwọ̀n bí ìwọ ti gbàgbé mi, tí iwọ sì ti fi mi sí ẹ̀yìn rẹ, ìwọ gbọdọ̀ gba àbájáde ìfẹ́kúfẹ́ àti aṣẹ́wó rẹ Olúwa sọ fún mi pé Ọmọ ènìyàn, ń jẹ́ ìwọ yóò ṣe ìdájọ́ Óhólà àti Óhólíbà Nítorí náà dojú kọ wọn nípa ìkórìíra tí wọn ń ṣe, nítorí wọn ti dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn Wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà pẹ̀lú àwọn orìṣà wọn kódà wọ́n fi àwọn ọmọ wọn tí wọn bí fúnni ṣe ìrúbọ, gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún wọn Bákan náà ni wọ́n ti ṣe èyí náà sí mi Ní àkókò kan náà wọn ba ibi mímọ́ mi jẹ́, wọ́n sì lo ọjọ́ ìsinmi mi ní àìmọ́ Ní ọjọ́ náà gan an wọ́n fi àwọn ọmọ wọn rúbọ sí àwọn òrìṣà, wọn wọ ibi mímọ́ mi lọ wọn sì lò ó ní ìlòkúlò Ìyẹn ní wọn ṣe ní ilé mi Wọn tilẹ̀ rán oníṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn, nígbà tí wọ́n dé, ìwọ wẹ ara rẹ fún wọn, ìwọ kún ojú rẹ, ìwọ sì fi ọ̀sọ́ iyebíye sára, Ìwọ jókòó lórí ibùsùn ti o lẹ́wà, pẹ̀lú tábìlì tí a tẹ́ ní iwájú rẹ lórí, èyí tí o gbé tùràrí àti òróró tí ó jẹ́ tèmi kà Ariwo ìjọ ènìyàn tí kò bìkítà wà ní àyíká rẹ̀ a mú Sábéánì láti ihà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin láti ara àwọn ọ̀pọ̀ èniyàn aláìníláárí, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ sí àwọn ọwọ́ obìnrin náà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, adé dárádárá sì wà ní orí wọn Lẹ́yìn náà mo sọ̀rọ̀ nípa èyí tí ó lo ara rẹ̀ ṣá nípa aṣẹ́wó ṣíṣe, Nísìnyí jẹ kí wọn lo o bí aṣẹ́wó, nítorí gbogbo ohun tí ó jẹ́ nìyẹn Wọn ba sùn bí ọkùnrin ti bá aṣẹ́wó sùn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sùn pẹ̀lú obìnrin onífẹ̀kúfẹ̀ẹ́, Óhólà àti Óhólíbà Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin olódodo yóò pàṣẹ pé kí wọ́n fi ìyà jẹ àwọn obìnrin tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè tí ó sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ nítorí pé aṣẹ́wó ni wọ́n ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí Mú àgbájọ àwọn ènìyàn kénìyàn wá sọ́dọ̀ wọn ki ó sì fi wọn lé ọwọ́ ìpayà àti ìkógun Àwọn ènìyànkénìyàn náà yóò sọ wọ́n ni òkúta, yóò sì gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà wọn wọn ó sì pa àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n ó sì jó àwọn ilé wọn kanlẹ̀ Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ni ilẹ̀ náà, kí gbogbo àwọn obìnrin le gba ìkìlọ̀ kí wọn kí ó ma sì ṣe fara wé ọ Ìwọ yóò sì jìyà fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì gba àbájáde àwọn ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí o dá Nígbà náà ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè Ìkòkò Ìdáná Náà Ní ọdún kẹsàn án, oṣù kẹwàá, ọjọ́ kẹwàá, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, kọ ọjọ́ náà sílẹ̀, ọjọ́ náà gan an, nítorí Ọba Bábílónì náà ti dojúti Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ yìí gan an Sì pa òwe yìí fún ilé ọlọ́tẹ̀ náà, sọ fún wọn pé Èyí yìí ni Olúwa Ọlọ́run wí  Gbé ìkòkò ìdáná náà ka iná Gbé e kaná kí o sì da omi sí i nínú Kó àwọn ègé ẹran tí a gé náà sínú rẹ̀, gbogbo àwọn ègé ẹran tí ó tóbi, itan àti apá Kó àwọn egungun tí ó dára jù sínú rẹ̀ Mú àwọn tí ó jọjú nínú agbo ẹran Kó àwọn egungun sí abẹ́ ẹ rẹ̀ sì jẹ́ kí ó hó dára dára sì jẹ́ kí àwọn egungun náà bọ̀ nínú rẹ̀  Nítorí báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí  Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà, fún ìkòkò náà tí èrúru wà nínú rẹ̀ tí èrúru kò dà kúrò lójú rẹ̀! Mú ẹran náà jáde ní ekìrí ekìrí má ṣe ṣà wọ́n mú  Nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ wà ní àárin rẹ̀ o dà á sí orí àpáta kan lásán kò dà á sí orí ilẹ̀, níbi ti erùpẹ̀ yóò ti bò ó Láti bá à le jẹ́ kí ìbínú kí ó dé láti gbẹ̀san mo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí orí àpáta kan lásán, kí o ma bà á wà ni bíbò  Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí  Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà! Èmi pàápàá yóò jẹ́ kí òkítì iná náà tóbi Nítorí náà kó igi náà jọ sí i, kí o sì fi iná sí i Ṣe ẹran náà dáadáa, fi tùràrí dùn ún ki o sì jẹ́ kí egungun náà jóná Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin iná kí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́n àti ki èérí rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀ kí èrúrú rẹ̀ le jó dànù Ó ti fi èké dá ara rẹ̀ lágara èrúrú rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀, èrúrú náà gan an yóò wà nínú iná  Nísìn yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èèrí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀  Èmi Olúwa ni ó sọ ọ́, yóò sì ṣe, èmi yóò sì ṣe é Èmi kì yóò pada sẹ́yìn bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọkàn mi padà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ, ni wọn yóò dá ọ lẹ́jọ́, ni Olúwa Ọlọ́run wí   Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá pé Ọmọ ènìyàn, kíyèsí i, mo mú ìfẹ́ ojú rẹ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, nípa lílù kan Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ gbààwẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sunkún, bẹ́ẹ̀ ni omijé ojú rẹ kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀ Má ṣe sunkún, má ṣe gbààwẹ̀ fún òkú Wé ọ̀já sí orí rẹ, sì bọ bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ má ṣe bo ètè ìsàlẹ̀ rẹ, ma ṣe jẹ oúnjẹ tí àwọn tí ń sọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà Báyìí ni mo sọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn ní òwúrọ̀, ní àṣálẹ́ ìyàwó mi sì kú Ní òwúrọ́ ọjọ́ kejì, mo ṣe bí a ti pàsẹ fún mi Lẹ́yìn náà àwọn ènìyàn bi mí léèrè pé, Ṣe o kò ni sọ fún wa ohun ti nǹkan wọ̀nyí ní láti ṣe pẹ̀lú wa Mo sọ báyìí fún wọn pé, Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé Sọ fún ilé Ísírẹ́lì, Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí Kíyèsí i, èmi yóò sọ ibi mímọ́ mi di ibi àìmọ́ títayọ agbára yín, ìfẹ́ ojú yín, ìkáànú yín, àti ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin tí ẹ̀yin fi sílẹ̀ sẹ́yìn yóò ṣubú nípa idà Ẹyin yóò sì ṣe bí mo ti ṣe Ẹ̀yin kì yóò bo ìsàlẹ̀ ojú yín tàbí jẹ oúnjẹ ti àwọn tí ń sọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà Ẹ̀yin yóò fi àwọn ọ̀já wé àwọn orí i yín àti àwọn bàtà ni ẹsẹ̀ yín, ẹ̀yin kì yóò sọ̀fọ̀ tàbí sunkún, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò ṣòfò dànù nítorí àwọn àìṣedédé yín, ẹ̀yin yóò sì máa kérora láàrin ara yín Ísíkẹ́ẹ̀lì yóò jẹ àmì fún un yín ẹ̀yin yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe Nígbà tí èyí bá sẹlẹ̀, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run Pẹ̀lúpẹ̀lù ìwọ, Ọmọ ènìyàn, kì yóò ha jẹ́ pé, ní ọjọ́ náà, nígbà ti mo bá gba agbára wọn, ayọ̀ wọn àti ògo wọn, ìfẹ́ ojú wọn, ohun tí wọn gbé ọkàn wọn lé, àti àwọn ọmọ ọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ obìnrin wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní ọjọ́ náà ẹni tí ó bá sálà yóò tọ̀ ọ́ wá láti sọ ìròyìn náà fún ọ Ní ọjọ́ náà ẹnu rẹ yóò sì sí ìwọ yóò sọ̀rọ̀, ìwọ kì yóò sì yadi mọ́ Báyìí ìwọ yóò jẹ́ àmì fún wọn wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ní Olúwa Àsọtẹ́lẹ̀ Òdì Sí Ámónì Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí àwọn ará Ámónì kí ó sì sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí wọn Sì wí fún àwọn ará Ámónì pé, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run tí ó wí pé Nítorí tí ìwọ wí pé, Á hà! Sí ibi mímọ́ mi nígbà tí ó di àìlọ́wọ̀ àti sí orí ilẹ̀ Ísírẹ́lì nígbà tí ó di ahoro àti sí ilẹ̀ Júdà, nígbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn, kíyèsí i, nítorí náà ni èmi yóò fi fi ọ lé àwọn ènìyàn ìlà oòrùn lọ́wọ́ ni ohun ìní Wọn yóò sì gbé ààfin wọn kalẹ̀ nínú rẹ, wọn yóò sì gbé ibùgbé wọn nínú rẹ wọn yóò jẹ èso rẹ, wọn yóò sì mu wàrà rẹ Èmi yóò sì sọ Rábà di ibùjẹ, fún àwọn ìbákasíẹ àti àwọn ọmọ Ámónì di ibùsùn fún agbo ẹran Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Nítorí pé ìwọ pàtẹ́wọ́, ìwọ sì jan ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ìwọ ń yọ̀ pẹ̀lú gbogbo àrankàn rẹ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi lé ọ, èmi yóò sì fi ọ fún àwọn aláìkọlà fún ìkógun Èmi yóò sì gé ọ kúrò láàrin àwọn ènìyàn, èmi yóò sì jẹ́ kí o parun kúrò ni ilẹ̀ gbogbo Èmi yóò sì pa ọ́ run, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Nítorí pé Móábù àti Séírì sọ wí pé, Wò ó, ilé Júdà ti dàbí gbogbo àwọn aláìkọlà, nítorí náà Èmi yóò sí Móábù sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Bétjẹ́símótì, Báálì-Méónì àti Kíríátaímù Èmi yóò fi Móábù pẹ̀lú àwọn ará Ámónì lé àwọn ènìyàn ìlà oòrùn ní ìní, kí a má bà á lè rántí àwọn ará Ámónì láàrin orílẹ̀ èdè gbogbo Èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣsẹ sí Móábù lára, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa   Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí pé Nítorí pé Édómù gbẹ̀san lára ilé Júdà, ó sì jẹ̀bi gidigidi nípa síse bẹ́ ẹ̀, nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Édómù èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko rẹ̀ Èmi yóò fi sófo láti Temanì dé Dédánì yóò ti ipa idà ṣsubú Èmi yóò gbẹ̀san lára Édómù láti ọwọ́ àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, wọn sì se ṣsi Édómù gẹ́gẹ́ bí ìbínú àti ìrunú mi wọn yóò mọ̀ ìgbẹ̀san mi ní Olúwa Ọlọ́run wí   Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí pé Nítorí tí àwọn ará Fílísítíà hùwà ẹ̀san tí wọ́n sì gbẹ̀san pẹ̀lú odì ní ọkàn wọn, àti pẹ̀lú ìjà gbangba àtijọ́ ní wíwá ọ̀nà láti pa Júdà run, nítorí náà báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí pé Èmi ti ṣetán láti na ọwọ́ mi jáde sí àwọn ará Fílísítíà Èmi yóò sì ké àwọn ará Kérétì kúrò, Èmi yóò sì pa àwọn tí ó kù ní etí kún run Èmi yóò sì gbẹ̀san ńlá lára wọn nípa ìbáwí gbígbóná wọn yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi ni Olúwa Nígbà tí èmi yóò gba ẹ̀san lára wọn   Àsọtẹ́lẹ̀ Òdì Sí Tírè Ní ọjọ kìn-ín-ní, oṣù kọ́kànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, nítorí pé Tírè sọ nípa Jérúsálẹ́mù pé, Áà! A fọ́ èyí tí í ṣe bodè àwọn orílẹ̀-èdè, a yí i padà sí mi, èmi yóò di kíkún, òun yóò sì di ahoro, nítorí náà, báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí Kíyèsí i, èmí dojú kọ ọ́ ìwọ Tírè, Èmi yóò sì jẹ́ kí orílẹ̀ èdè púpọ̀ dide sí ọ, gẹ́gẹ́ bí òkun tíi ru sókè Wọn yóò wó odi Tírè lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀ Èmi yóò sì ha ẹrùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàárin òkun, ní Olúwa Ọlọ́run wí Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀ èdè Ìlú tí ó tẹ̀dó sí, ní àárin gbùngbùn ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó fi idà sọ ọ́ di ahoro Nígbà náà ní wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Nítorí báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí Kíyèsí i, láti ìhà àríwá ni èmi yóò ti mú Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, Ọba àwọn Ọba, dide sí Tírè pẹ̀lú ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun Yóò sì fi idà ṣá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkítì tì ọ́, yóò sì gbé apata sókè sí ọ Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀ Àwọn ẹsin rẹ̀ yóò pọ̀ dé bí pé wọn yóò fi eruku bò ọ́ mọ́lẹ̀ Àwọn ògiri rẹ yóò mì tìtì fún igbe àwọn ẹṣin ogun kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kẹ̀kẹ́ ogun nígbà tí ó bá wọ ẹnu ọ̀nà odi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń wọ ìlú láti inú àwọn ògiri rẹ̀ ti o di fífọ́ pátapáta Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin rẹ̀ ni yóò fi tẹ gbogbo òpópónà rẹ mọ́lẹ̀ yóò fi idà pa àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọ̀wọ́n rẹ ti o lágbára yóò wó palẹ̀ Wọn yóò kó ọrọ̀ rẹ, wọn yóò sì fi òwò rẹ ṣe ìjẹ ogun wọn yóò sì wó odi rẹ lulẹ̀, wọn yóò sì ba àwọn ilé rẹ dídára jẹ́, wọn yóò sì kó àwọn òkúta rẹ̀, àti igi ìtì ìkọ́lé rẹ̀, àti erùpẹ̀ rẹ̀, dà sí inú òkun Èmi yóò sì mú ariwo orin rẹ̀ dákẹ́ àti ìró dùùrù orin rẹ̀ ni a kì yóò gbọ́ mọ́ Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí èmi Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ ní Olúwa Ọlọ́run wí Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí sí Tírè Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń sẹlẹ̀ ní inú rẹ Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ aládé etíkun yóò sọ̀ kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn tì wọn yóò sì bọ́ àwọn ẹ̀wù wọn tí a ṣiṣẹ́ ọ̀nà sí lára kúrò Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jòkòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́ Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé  Báwo ni a se pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkí ìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀! Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogbo òun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀ ìwọ gbé ẹ̀rù rẹ lórí gbogbo olùgbé ibẹ̀ Nisin yìí erékùṣù wárìrì ní ọjọ́ ìṣubú rẹ erékùṣù tí ó wà nínú òkun ni ẹ̀rù bà torí ìṣubú rẹ Èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́, nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́ Èmi yóò sì gbé ọ ibi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè Èmi yóò ṣe ọ ní ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì sí mọ́ Bí a tilẹ̀ wá ọ, ṣíbẹ̀ a kì yóò tún rí ọ mọ́, ní Olúwa Ọlọ́run wí Ìpohùn-Réré Ẹkún Fún Tírè Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún fún Tírè Sọ fún Tírè, tí a tẹ̀dó sí ẹnu bodè òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù Èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí  Ìwọ Tírè wí pé Ẹwá mi pé Ààlà rẹ wà ní àárin òkun àwọn ọ̀mọ̀lé rẹ ti mú ẹwà rẹ pé Wọn ti fi pákó firi ti Sénárì kan gbogbo ọkọ̀ rẹ, wọ́n ti mú kédárì ti Lébánónì wá láti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ Nínú igi Oákù ti Báṣánì ní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ òbèlè rẹ̀ ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lú igi bókísì láti erékùsù Kítímù wá Asọ funfun dáradára tí a fi abẹ́rẹ́ ṣiṣẹ́ ọ̀nà sí lára láti Éjíbítì wá ni èyí tí ìwọ ta láti se okun ọkọ̀ aṣọ aláró àti elésèé àlùkò láti erékùṣù ti Èlíṣà ni èyí tí a fi bò ó Àwọn ará ìlú Sídónì àti Árífádì ni àwọn ìtukọ̀ rẹ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tírè, tí wọ́n wà nínú rẹ ni àwọn àtukọ̀ rẹ Àwọn àgbà Gíbálì, àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀, wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ, gbogbo ọkọ̀ ojú òkun àti àwọn atukọ̀-òkun wá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀  Àwọn ènìyàn Páṣíà, Lídíà àti Pútì wà nínú jagunjagun rẹ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ Wọ́n gbé àpáta àti àsíborí wọn ró sára ògiri rẹ, wọn fi ẹwà rẹ hàn Àwọn ènìyàn Árífádì àti Hélékì wà lórí odi rẹ yíká àti àwọn akọni Gámádì, wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ wọn ti mú ẹwà rẹ pé  Táṣíṣì ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin tanúnganran àti òjé fún ọjà títà rẹ̀  Àwọn ará Gíríkì, Túbálì, Jáfánì àti Méṣékì, ṣòwò pẹ̀lú rẹ wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàsípààrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ  Àwọn ti ilé Béti Tógárímà ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin-ogun àti ìbàákà ṣòwò ní ọjà rẹ  Àwọn ènìyàn Ródísì ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ onibárà rẹ̀ wọ́n mú eyín-erin àti igi ébónì san owó rẹ  Árámù ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀ wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elésèé àlùkò, iṣẹ́ ọ̀nà tí a fi abẹ́rẹ́ ṣe, asọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ  Júdà àti Ísírẹ́lì, àwọn ni oníṣòwò rẹ wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Mínnítì, àkàrà àdídùn pannági, oyin, epo àti ìpara olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ  Dámásíkù, ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ ní ti ọtí wáìnì tí Helíbónì, àti irun àgùntàn funfun  Àwọn ará Dánì àti Gíríkì láti Úsálì ra ọjà títà rẹ irin dídán, káṣíà ati kálámù ni àwọn ohun pàsípààrọ̀ ní ọjà rẹ  Dédánì ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn  Àwọn ará Árábù àti gbogbo àwọn ọmọ aládé Kédárì àwọn ni àwọn onibárà rẹ ní ti ọ̀dọ́ àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbárà rẹ  Àwọn oníṣòwò ti Ṣébà àti Rámà, àwọn ni oníṣòwò rẹ wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà  Áránì àti Kánnà àti Édénì, àwọn onísòwò Ṣébà, Ásúrù àti Kílímádì, ni àwọn oníṣòwò rẹ Wọ̀nyí ní onírúurú nǹkan aṣọ aláró, àti oniṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ oníyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kédárì ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ  Àwọn ọkọ̀ Táṣíṣì ní èrò ní ọjà rẹ a ti mú ọ gbilẹ̀ a sì ti ṣe ọ́ lógo ní àárin gbungbun òkun Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọ wá sínú omi ńlá Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ ní àárin gbùngbùn òkun Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ, àwọn atọ́kọ̀ rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ Àwọn oníbárà rẹ àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹ àti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹ tí ó wà ní àárin rẹ yóò rì sínú àárin gbùngbùn òkun ní ọjọ́ ìparun rẹ Ilẹ̀ etí òkun yóò mì nítorí ìró igbe àwọn atọ́kọ̀ rẹ Gbogbo àwọn alájẹ̀ àwọn atukọ̀ àti àwọn atọ́kọ̀ ojú òkun yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn, wọn yóò dúró lórí ilẹ̀ Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọ wọn yóò sì sunkún kíkorò lé ọ lórí wọn yóò ku eruku lé orí ara wọn wọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹ wọn yóò wọ aṣọ yíya wọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lú ìkoro ọkàn nítorí rẹ pẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùn réré ẹkún fún ọ wọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé Ta ni ó dàbí Tírè èyí tí ó parun ní àárin òkun Nígbà tí ọjà títà rẹ ti òkun jáde wá ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè lọ́rùn ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀ Ní ìsinsìn yìí tí òkun fọ ọ túútúú nínú ibú omi nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ ní àárin rẹ, ni yóò ṣubú Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbé ní erékùṣù náà sí ọ àwọn ọba wọn yóò sì dìjì, ìyọnu yóò sì yọ ní ojú wọn Àwọn oníṣòwò láàrin àwọn orílẹ̀ èdè dún bí ejò sí ọ ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù ìwọ kì yóò sì sí mọ́ láéláé   Àsọtẹ́lẹ̀ Òdì Sí Ọba Tírè Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tírè pé, Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí  Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè simi ìwọ wí pé, Èmi ni Ọlọ́run Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà ní àárin gbùngbùn òkun Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run Ìwọ gbọ́n ju Dáníẹ́lì lọ bí Ṣé kò sí àsírí kan tí ó pamọ́ fún ọ Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀ àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, ọkàn rẹ gbé sókè Nitorí ọrọ̀ rẹ  Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí  Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n, pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run Èmi yóò mú kí àwọn àjòjì dìde sí ọ, ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀ èdè wọn yóò yọ idà wọn sí ọ ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́ Wọn yóò mú ọ sọ̀ kalẹ̀ wá sínú ihò ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná àwọn tí a pa ní àárin òkun Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, Èmi ni Ọlọ́run, ní ojú àwọn tí ó pa ọ́ Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run, ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́ Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà ní ọwọ́ àwọn àjòjì Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Ọlọ́run wí   Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tírè kí ó sì sọ fún un pé Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí  Ìwọ jẹ́ àpẹrẹ ìjẹ́pípé náà o kún fún ọgbọ́n, o sì pé ní ẹwà Ìwọ ti wà ní Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run onírúurú òkúta iyebíye ni ìbora rẹ sárídù, tópásì àti díámọ́ndì, bérílì oníkì, àti jásípérì, sáfírè, émérálídì àti káríbúnkílì, àti wúrà ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà láti ara wúrà, ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù, torí èyí ni mo fi yàn ọ́ Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run ìwọ rìn ni àárin òkúta amúbína, Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ láti ọjọ́ tí a ti dá ọ títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ ìwọ kún fún ìwà ipá ìwọ sì dẹ́sẹ̀ Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run Èmi sì pa ọ run, ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárin òkúta amúbínà Ọkàn rẹ gbéraga nítorí ẹwà rẹ Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́ nítorí dídára rẹ Nítorí náà mo le ọ sórí ayé mo sọ ọ di awò ojú níwájú àwọn ọba Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìsòótọ́ rẹ ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́ Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run, èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀ lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́ Gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó mọ̀ ọ́ ní ẹnu ń yà sí ọ ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù ìwọ kì yóò sì sí mọ́ láéláé   Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sídónì kí o sì ṣọtẹ́lẹ̀ sí i Kí ó sì wí pé Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí  Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sídónì, a ó sì ṣe mí lógo láàárin rẹ Wọn yóò, mọ̀ pé èmi ní Olúwa , Nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ, Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-àrùn sínú rẹ èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn ní ìgboro rẹ ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárin rẹ pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa  Kì yóò sì sí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run  Èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí Nígbà tí èmi yóò bá ṣa àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàárin wọn lójú àwọn aláìkọlà Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkalára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jákọ́bù Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígba tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi sẹ sí ara àwọn tí ń ṣáátá wọn ní gbogbo àyíká wọn Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn   Àsọtẹ́lẹ̀ Òdì Sí Éjíbítì Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹ́wàá, ọdún kẹ́wàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Fáráò ọba Éjíbítì kí ó sì sọ àṣọ̀tẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Éjíbítì Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí  Èmi lòdì sí ọ, Fáráò ọba Éjíbítì ìwọ dírágónì ńlá inú òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí àárin àwọn odò ṣíṣàn rẹ èyí tí ó sọ wí pé, Tèmi ni odò Náílì èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrin àwọn odò rẹ, àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ Èmi yóò sọ ọ́ nù sí ihà ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè Èmi ti fi ọ ṣe oùnjẹ fún àwọn ẹranko igbó àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ijíbítì yóò mọ pé Èmi ni Olúwa  Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Ísírẹ́lì Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n  Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí kéyèsí i Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ Ilẹ̀ Éjíbítì yóò di ihà àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa  Nítorí tí ìwọ wí pé, Tèmi ni odò Náílì Èmi ni mo ṣe é, Nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ Éjíbítì di píparun àti ahoro, pátapáta, láti Mígídólì lọ dé Ásíwánì, dé ààlà ilẹ Kúṣì Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún Èmi yóò sọ ilẹ Éjíbítì di ọ̀kan ní àárin àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Éjíbítì ká sáàárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárin gbogbo ilẹ̀  Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Éjíbítì jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Éjíbítì padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Pátírósì, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀ Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹ̀lẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè nítorí èmi ni ó dín wọn kù, ti wọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́ Éjíbítì kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Ísírẹ́lì mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedédé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́ Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run   Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, Nebukadinésárì ọba Bábílónì mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tírè Gbogbo ori pá, àti gbogbo èjìká bó, ṣíbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owo ọ̀yà gbà láti Tírè fún wa, fún ìrú ti a ti sìn Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Kíyèsí i, Èmi yóò fi Éjíbítì fún Nebukadinésárì ọba Bábílónì, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀ Èmi ti fi Éjíbítì fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni Olúwa Ọlọ́run wí Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ilé Ísírẹ́lì ní agbára, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárin wọn Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ìkìlọ̀ Sí Ísírẹ́lì Síwájú sí i, ó sọ fún mi pé, Ọmọ ènìyàn, jẹ ohun tí ó wà níwájú rẹ, jẹ ìwé tí a ká yìí kí o sì lọ fi bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ Mo sì ya ẹnu mi, ó sì mú mi jẹ ìwé kíká náà Ó tún sọ fún mi pé, Ọmọ ènìyàn, jẹ ìwe tí mo fún ọ yìí, fi bọ́ inú àti ikùn rẹ Nígbà náà ni mo jẹ ẹ́, dídùn rẹ̀ dàbí oyin ní ẹnu mi Ó sì tún sọ fún mi pé Ọmọ ènìyàn, lọ ni ìsinsinyìí bámi sọ ọ̀rọ̀ mi fún ìle Ísírẹ́lì A kò rán ọ sí àwọn tó ń sọ èdè àjèjì tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, ṣùgbọ́n orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì ni mo rán ọ sí kì í ṣe sí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń sọ àjèjì èdè tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn le fún ọ láti gbọ́ yé Dájúdájú bí mo bá rán ọ sí wọn, wọn ì bá sì fetí sílẹ̀ sí ọ Ṣùgbọ́n ilé Ísírẹ́lì kò fẹ́ gbọ́ tìrẹ nítorí pé wọn kò fẹ́ láti gbọ́ tèmi, torí pé aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle ni gbogbo ilé Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n bí i ti wọn lèmi náà yóò ṣe jẹ́ kí ojú àti ọkàn rẹ le Èmi yóò ṣe iwájú orí rẹ bí òkúta tó le jùlọ àni tó le ju òkúta ìbọn lọ Má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí jẹ́ kí wọn ó dáyà já ọ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n Ó sì sọ fún mi pé, Ọmọ ènìyàn, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, kí o sì gba gbogbo ọ̀rọ̀ yìí sí ọkàn rẹ Lọ nísinsìnyìí sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ tó wà ní ìgbèkùn Sọ fún wọn pé báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn kò gbọ́ Nígbà náà ni Ẹ̀mí gbé mi sókè, mo sì gbọ́ ohùn ìró ńlá lẹ́yìn mi-tó sọ pé, kí a gbé ògo Olúwa ga láti ibùgbé rẹ̀ wá! Bẹ́ẹ̀ ni mo tún gbọ́ ariwo ìyẹ́ apá àti kẹ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà pẹ̀lú ariwo tó dàbí àrá ńlá Ẹ̀mí náà sì gbé mi sókè, ó sì mú mi lọ, mo lọ pẹ̀lú ọkàn kíkorò àti ìbínú nínú ẹ̀mí mi, pẹ̀lú ọwọ́ líle Olúwa ni ara mi Nígbà náà ni mo lọ sí etí odò Kébárì níbi tí àwọn ìgbèkùn ń gbé ni Teli-Ábíbì Níbẹ̀ níbi tí wọ́n ń gbé, mo jókòó láàrin wọn pẹ̀lú ìyànu, fún ọjọ́ méje Lẹ́yìn ọjọ́ méje, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, mo ti fi ọ́ ṣe òlùṣọ́ fún ìle Ísírẹ́lì nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, fún wọn ní ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé dájúdájú, Ìwọ yóò kú, tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún ènìyàn búburú yìí láti dáwọ́ ìwà ibi rẹ̀ dúró, kí o sì gba ẹ̀mí rẹ̀ là, ènìyàn búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún ènìyàn búburú, tí ó kọ̀ tí kò fi ìwà búburú rẹ̀ sílẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n ọrùn tìrẹ ti mọ́ Bákan náà, bí olódodo kan bá yípadà, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àìsòdodo, tí mo sì fi ohun ìkọ̀sẹ̀ sí ọ̀nà rẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ Nítorí pé ìwọ kọ̀ láti kìlọ̀ fún un, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a ó gbàgbé gbogbo ìwà rere tó ti hù tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún olódodo tó sì dáwọ́ ìwà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ dúró, dájúdájú òun yóò yè nítorí pé ó ti gba ìkìlọ̀, ọrùn tìrẹ sì mọ́ Ọwọ́ Olúwa wà lára mi níbẹ̀, ó sì wí fún mi pé, Dìde, lọ sí ibi tí ó tẹ́jú, èmi yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀ Mo sì dìde mo lọ sí ibi tí ó tẹ́jú Ògo Olúwa dúró níbẹ̀, ó dàbí irú ògo tí mo rí létí odò Kébárì, mo sì dojúbolẹ̀ Nígbà náà ni Ẹ̀mí wọ inú mi, tí ó sì tún gbé mi dúró Ó sì wí fún mi pé Lọ, ti ara rẹ mọ́ inu ilé rẹ ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, wọn yóò fi okùn dè ọ́ mọ́lẹ̀ dé ibi pé ìwọ kò ní í le rìn káàkiri láàrin àwọn ènìyàn Èmi yóò mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ àjà ẹnu rẹ, tó bẹ́ẹ̀ ti ìwọ yóò wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ Ìwọ kò sì ní lè bá wọn wí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ní wọn Ṣùgbọ́n nígbà tí èmi bá bá ọ sọ̀rọ̀, Èmi yóò sí ọ lẹ́nu, ìwọ yóò sì sọ fún wọn pé, Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí Ẹni tó bá fẹ́ kí ó gbọ́, ẹni tó bá fẹ́ kọ̀, kó kọ̀ nítorí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n Ìpohùnréré Ẹkún Fún Éjíbítì Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí  Pohùnréré ẹkún kí o sì wí pé, Ó ṣe fún ọjọ́ náà! Nítorí ọjọ́ náà sún mọ́ tòsí àní ọjọ́ Olúwa sún mọ́ tòsí Ọjọ́ tí ọjọ́ ìkùukùu ṣú dúdú, àsìkò ìparun fún àwọn aláìkọlà Idà yóò wá sórí Éjíbítì ìrora ńlá yóò sì wá sórí Kúṣì Nígbà tí àwọn tí a pa yóò subú ní Éjíbítì wọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọ ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀ Kúṣì àti Pútì, Lídíà àti gbogbo Árábù, Líbíyà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ ìlérí yóò ṣubú nípa idà papọ̀ pẹ̀lú Éjíbítì  Èyí yìí ní Olúwa wí  Àwọn alejò Éjíbítì yóò ṣubú agbára ìgbéraga rẹ yóò kùnà láti Mígídólì títí dé Ásúwánì wọn yóò ti ipa idà ṣubú láàárin rẹ ní Olúwa Ọlọ́run wí Wọn yóò sì wà lára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro, ìlú rẹ yóò sì wà ní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa , nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ijíbítì tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun  Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kúsì kúrò nínú ìtẹ́lọ́rùn rẹ̀ Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Éjíbítì Kíyèsí i, ó dé  Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí  Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn Éjíbítì láti ọwọ́ Nébukadinésárì ọba Bábílónì Òun àti àwọn ológun rẹ̀ ẹ́rù àwọn orílẹ̀-èdè ní a o mú wá láti pa ilẹ náà run Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Éjíbítì ilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa Èmi yóò mú kí àwọn odò Náílì gbẹ Èmi yóò sì ta ilẹ náà fún àwọn ènìyàn búburú láti ọwọ́ àwọn àjòjì ènìyàn Èmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò Èmi Olúwa ni ó ti sọ ọ́  Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí  Èmi yóò pa àwọn òrìṣà run Èmi yóò sì mú kí òpin dé bá ère òrìṣà gbígbẹ́ ni Nófì kò ní sí ọmọ aládé mọ́ ní Éjíbítì, Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà Èmi yóò sì mú kí Pátírọ́sì di ahoro èmi yóò fi ina sí Sóánì èmi yóò sì fi ìyà jẹ Tébésì Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pélúsíómù ìlú odi Éjíbítì èmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Jépésì kúrò Èmi yóò ti iná bọ Éjíbítì Pélúsíómù yóò japoró ní ìrora Èfúùfù yóò jà ní Tébésì Mémìfísì yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Hẹ́lópónísè àti Búbásítì yóò ti ipa idà subú wọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tápárebì nígbà tí mo bá já àjàgà Éjíbítì kúrò níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópin wọn yóò fi ìkùukùu bò ó àwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn Nítorí náà Èmi yóò mú ki ìjìyà wá sórí Éjíbítì, wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa   Ní ọjọ́ keje osù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, Èmi ti ṣe apa Fáráò Ọba Éjíbítì A kò ì tí ì di apá náà papọ̀ láti mu kí ó san, a ko sì ti di i si àárin igi pẹlẹbẹ kí o lè ni agbára tó láti di idà mú Nítorí náà, báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi lòdì sí Fáráò Ọba Éjíbítì Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀ Èmi yóò sì fọ́n àwọn ènìyàn Éjíbítì ká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká gbogbo ilẹ̀ Èmi yóò mú kí apá Ọba Bábílónì ní agbára, èmi yóò sì fi idà mi sí ọwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ apá Fáráò, yóò sì kérora níwájú rẹ̀ bí ọkùnrin tí a ṣá ní àṣápa Èmi yóò mú kí apá Ọba Bábílónì lé, ṣùgbọ́n apá Fáráò yóò sì rọ Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa , nígbà tí mo bá mú idà mi sí ọwọ́ Ọba Bábílónì yóò sì fí idà náà kọlu Éjíbítì Èmi yóò fọ́n àwọn ara Éjíbítì ká sí àárin orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí àárin orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí gbogbo ilẹ̀ Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Òpépé Igi Sédárì Ni Lébánónì Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kẹ́ta ọdún kọkànlá, ọrọ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, sọ fún Fáráò Ọba Éjíbítì àti sí ìjọ rẹ̀  Ta ní a le fi wé ọ ní ọlá ńlá Kíyèsí Ásíríà, tí ó jẹ́ òpépé igi ni Lébánónì ní ìgbà kan rí, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣe ìji bo igbó náà tí ó ga sókè, òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà Omi mú un dàgbà sókè orísun omi tí ó jìnlẹ̀ mú kí o dàgbà sókè àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká, ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío ju gbogbo igi orí pápá lọ Ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn, wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ẹyẹ ojú ọ̀run kọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀ gbogbo ẹranko ìgbẹ́ ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ gbogbo orílẹ̀ èdè ńlá ń gbé abẹ́ ìjì rẹ̀ Ọlá ńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́, pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀, nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà Àwọn òpépé igi nínú ọgbà Ọlọ́run kò lè è bá a dọ́gba, tàbí kí àwọn igi firi ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀, tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀, kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run tí ẹwà rẹ̀ ṣe déédé pẹ̀lú rẹ̀ Mo mú kí ó ní ẹwà pẹ̀lú ẹ̀ka lọ́pọ̀lọpọ̀ tó fi jẹ́ ìlara àwọn igi gbogbo ní Édẹ́nì tí í ṣe ọgbà Ọlọ́run  Nítorí náà, èyí yìí ńi Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Nítorí pé ó ga lọ sókè fíofío, tí ó sì gbé òkè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn kọ́, àti nítorí pé gíga rẹ mú kí ó gbéraga, Mo fi lé alákóso àwọn orílẹ̀ èdè náà lọ́wọ́, fún un láti fi ṣe ẹ̀tọ́ fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀ Mo pa á tì sí ẹ̀gbẹ́ kan, àwọn orílẹ̀ èdè àjòjì aláìláàánú jùlọ ké e lulẹ̀, wọn sì fi kalẹ̀ Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣubú sórí òkè àti sí gbogbo àárin àwọn òkè àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí ó ṣẹ nà sílẹ̀ ní gbogbo àlàfo jíjìn ilẹ̀ Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ ayé jáde kúrò ní abẹ́ ìjì rẹ̀ wọn sì fi sílẹ̀ Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ni orí igi tí ó subú lulẹ̀ náà, gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́ wà ní àárin ẹ̀ka rẹ̀ Nítorí náà kò sí igi mìíràn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tí ó lè fi ìgbéraga ga sókè fíofío, tí yóò sì gbé sókè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ Kò sí igi mìíràn tí ó ní omi tó bẹ́ẹ̀ tí ó lè ga tó bẹ́ ẹ̀ gbogbo wọn ni a kádàrá ikú fún, fún ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ní àárin àwọn alààyè ènìyàn, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ọ̀gbun ní ìsàlẹ̀  Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí ní ọjọ́ ti a mú u wá sí isà òkú mo fi ọ̀fọ̀ ṣíṣe bo orísun omi jínjìn náà Mo dá àwọn ìṣàn omi rẹ̀ dúró, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi rẹ̀ ní a dí lọ́nà Nítorí rẹ̀ mo fi ìwúwo ọkàn wọ Lẹ́bánónì ní aṣọ, gbogbo igi ìgbẹ́ gbẹ dànù Mo mú kí orílẹ̀ èdè wárìrì sì ìró ìṣubú rẹ̀ nígbà tí mo mú un wá sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun ìṣàlẹ̀ Nígbà náà gbogbo igi Édẹ́nì, àṣàyàn àti èyí tí ó dára jùlọ nínú Lẹ́bánónì, gbogbo igi tí ó ní omi dáadáa ni a tù nínú ni ayé ìsàlẹ̀ Àwọn tí ó ń gbé ní abẹ́ ìjì rẹ̀, àwọn àjòjì rẹ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè náà, ti lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú rẹ̀, ní dídárapọ̀ mọ́ àwọn tí a fi idà pa  Èwo lára igi Édẹ́nì ní a lè fi wé ọ ní dídán àti ọlá ńlá Síbẹ̀ ìwọ, gan an wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi Édẹ́nì lọ sí ìṣàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ yóò sùn ni àárin àwọn aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa  Èyí yìí ní Fáráò àti ìjọ rẹ̀, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí   Ìpohùnréré Ẹkún Fún Fáráò Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kejìlá, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Fáráò Ọba Éjíbítì kí o sì wí fún un  Ìwọ dàbí kìnnìún láàárin àwọn orílẹ̀ èdè náà ìwọ dàbí ohun abanilẹ́rù inú àwọn okun to ń lọ káàkiri inú àwọn odò rẹ, ìwọ fi ẹsẹ rẹ tẹ omi láti mú kí àwọn odò ní ẹrẹ̀  Èyí yìí ńi Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí  Pẹ̀lu ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyàn Èmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́ wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀ èmi yóò sì fà ọ́ sókè sí orí pápá gbangba Èmi yóò jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ní orí rẹ Gbogbo àwọn ẹranko ayé yóò fi ìwọra gbé ara wọn mù lórí rẹ Èmi yóò tan ẹran ara rẹ ká sórí àwọn òkè gíga ìyókù ara rẹ ní wọn yóò fi kún àwọn àárin àwọn òkè gíga Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń ṣàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náà gbogbo ọ̀nà sí orí àwọn òkè gíga, àwọn àlàfo jínjìn ní wọn yóò kún fún ẹran ara rẹ Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn èmi yóò sì fi ìkùukùu bo oòrùn òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ rẹ, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò í tí ì mọ̀ Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rù bà ọ́, àwọn Ọba wọn yóò sì wárìrì fún ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ, nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ ìkọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ  Nítorí èyí yìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí  Idà Ọba Bábílónì yóò wá sí orí rẹ, Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ó tí ipa idà àwọn alàgbà ènìyàn ṣubú àwọn orílẹ̀ èdè aláìláàánú jùlọ Wọn yóò tú ìgbéraga Éjíbítì ká, gbogbo ìjọ rẹ ní a óò dá ojú wọn bolẹ̀ Gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ ni èmi yóò parun ní ẹgbẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kì i ṣe ẹsẹ̀ ènìyàn ní yóò tẹ ibẹ̀ ẹsẹ̀ ẹran ọ̀sìn kì yóò sì mú kí ibẹ̀ ni arọ̀fọ̀ Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòrò kí àwọn odò rẹ̀ kí o ṣàn bí epo, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Nígbà tí mo bá sọ Éjíbítì di ahoro, tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀, nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Èyí yìí ni ẹkún tí a óò sun fún un Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀ èdè yóò sun ún nítorí Éjíbítì àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún ìjọ Éjíbítì kí o sì ránsẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀ èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò Sọ fún wọn, Ǹjẹ ìwọ ní ojú rere jù àwọn tí o kù lọ Lọ sí ìsàlẹ̀ kí a sì tẹ́ ọ sí àárin àwọn aláìkọlà náà Wọn yóò ṣubú láàárin àwọn tí a fi idà pa A fa idà yọ jẹ́ kí a wọ́ Éjíbítì kúrò pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀ Láti inú isà òkú alágbára tí í ṣe aṣáájú yóò sọ nípa Éjíbítì àti àwọn àlejò rẹ̀, Wọn ti wá sí ìsàlẹ̀, wọn sì sùn pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa Ásíríà wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo jagun jagun rẹ̀ àwọn isà òkú àwọn tí a ti pa sì yí i ká, gbogbo àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú Isà òkú wọn wà ní ibi tí ó jìnlẹ̀ gan an nínú kòtò Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè ní a pa, tí ó ti ipa idà ṣubú Élámù wà níbẹ̀, o yí isà òkú rẹ̀ ká pẹ̀lú gbogbo ijọ rẹ̀ Gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè lọ sí ìsàlẹ̀ láìkọlà sí abẹ́ ilẹ̀ Wọ́n gba ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò A ṣe ibùsùn fún un láàárin àwọn tí a pa, pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀ tí ó yí isà òkú ká Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, tí a fi idà pa Nítorí pé a tan ẹ̀rù wọn ká ilẹ̀ alààyè, wọn ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a pa Méṣékì àti Túbálì wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọ wọn yí isà òkú wọn ká Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, wọ́n fi idà pa wọ́n nítorí ẹ̀rù ti wọn tàn ká ilẹ̀ alààyè Ṣé wọn kò sùn pẹ̀lú àwọn ọ̀gágun aláìkọlà tí ó ti ṣubú, tí o lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú ohun ìjà, tí a sì fi idà wọn sí ìgbérí wọn Ìjìyà fún ẹ̀sẹ̀ wọn sinmi ní orí egungun wọn, ẹ̀rù àwọn ọ̀gágun ti wà káàkiri ilẹ̀ alààyè Ìwọ náà, Fáráò, ní yóò ṣẹ, ti yóò dùbúlẹ̀ láàárin aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa Édómù wà níbẹ̀, àwọn Ọba rẹ̀ àti gbogbo ọmọbìnrin Ọba bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní agbára, a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa Wọn dùbúlẹ̀ pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn ti o lọ sínú kòtò Gbogbo àwọn ọmọ aládé ilẹ̀ àríwá àti gbogbo àwọn ará Sídónì wà níbẹ̀ wọn lọ sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí a pa ní ìtìjú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ṣe okùnfà ẹ̀rù pẹ̀lú agbára wọn Wọn sùn ní àìkọlà pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa, wọn sì ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò Fáráò, òun àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ óò rí wọn, a yóò sì tù ú nínú nítorí gbogbo ìjọ rẹ̀ tí a fi idà pa, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè, Fáráò àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni a óò tẹ́ sí àárin aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ìsíkẹ́ẹ̀lì Alóre Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ kí ó sì sọ fún wọn Nígbà tí mo bá fi idà kọlu ilẹ̀ kan, tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yan ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin wọn láti jẹ́ alóre wọn, tí ó sì rí i pé idà ń bọ̀ lórí ilẹ̀ náà, tí ó sì fọn ìpè láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, nígbà náà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ìpè ṣùgbọ́n tí kò gbọ́ ìkìlọ̀, tí idà náà wá tí ó sì gba ẹ̀mí rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀ Nítorí tí ó gbọ́ ohùn ìpè ṣùgbọ́n tí kò sì gbọ́ ìkìlọ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí ara rẹ̀ Tí ó bá gbọ́ ìkìlọ̀, òun ìbá ti gba ara rẹ̀ là Ṣùgbọ́n bí alóre bá rí idà ti o ń bọ̀, tí kò sì fọn ìpè láti ki àwọn ènìyàn nílọ̀, tí idà náà wá, tí ó sì gba ẹ̀mí ọ̀kan nínú wọn, a óò mú ọkùnrin náà lọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n èmi yóò bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ Ọmọ ènìyàn, èmi fi ọ ṣe alóre fún ilé Ísírẹ́lì nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, kí o sì fún wọn ni ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi Nígbà ti mo bá sọ fún ẹni búburú pé, A! ẹni búburú, ìwọ yóò kú dandan, ti ìwọ kò sì sọ̀rọ̀ síta láti yí i lọ́kàn padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ẹni búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èmi yóò sì bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kìlọ̀ fún ẹni búburú láti yí padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, tí oun kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, òun yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ti gba ọkàn rẹ̀ là Ọmọ ènìyàn sọ fún ilé Ísírẹ́lì, Èyí yìí ní ìwọ sọ Àwọn ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ wa tẹ orí wa ba, àwa sì ń sòfò dànù nítorí wọn Bá wó wa ni a ṣe lè yè   Ṣọ fún wọn pé, Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, èmi kò ní inú dídùn sí ikú ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, kí wọ̀nyí padà kúrò ní ọ̀nà wọn gbogbo kì wọn kì ó sì yè Yí! Yípadà kúrò ni ọ̀nà búburú gbogbo! Kí ló dé tí ìwọ yóò kú Áà! Ísírẹ́lì Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ, Ìsòdodo ti olódodo ènìyàn kì yóò gbà á nígbà tí òun bá ṣe àìgbọ́ràn, ìwà búburú ènìyàn búburú kì yóò mú kí o ṣubú nígbà tí ó bá yí padà kúrò nínú rẹ̀ Bí olódodo ènìyàn bá ṣẹ̀, a kò ni jẹ́ kí ó yè nítorí òdodo rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ Bí mo bá sọ fún olódodo ènìyàn pé òun yóò yè, ṣùgbọ́n nígbà náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ̀ tí ó sì ṣe búburú, a kò ní rántí ìkankan nínú iṣẹ́ òdodo tí o ti ṣe sẹ́yìn òun yóò kú nítorí búburú tí ó ṣe Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, Ìwọ yóò kú dandan, ṣùgbọ́n tí ó bá yípadà kúrò nínú ẹsẹ̀ rẹ̀, ti o sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí o yẹ Tí ó bá mu ògo padà, tí o sì da ohun tí o ti jí gbé padà, tí ó sì tẹ̀lé òfin tí ó ń fún ni ní ìyè, tí kò sì ṣe búburú, òun yóò yè dandan òun kì yóò kú A kò ní rántí ìkan nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá Ó ti ṣe èyí tí ó tọ àti èyí tí o yẹ òun yóò sì yè dájúdájú Síbẹ̀ àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ sọ pé, ọ̀nà Olúwa kò tọ́ Ṣùgbọ́n ọ̀nà tí àwọn ní ó tọ́ Bí olódodo ènìyàn ba yípadà kúrò nínú òdodo rẹ̀, tí o sì ṣe búburú, òun yóò kú nítorí rẹ̀ Bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú búburú rẹ̀, tí ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ, òun yóò yè nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ Ṣíbẹ̀, ilé Ísírẹ́lì ìwọ wí pé, ọ̀nà Olúwa ki i ṣe òtítọ́ Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ ṣe rí Ní ọjọ́ karùn ún oṣù kẹ́wàá, ọdún kejìlá ìkólọ wa, ọkùnrin kan tí ó sá kúrò ni Jerúsálẹ́mù wá sọ́dọ̀ mi, ó sì wí pé, Ìlú ńlá náà ti ṣubú! Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ku ọ̀la tí ẹni tí ó sálọ náà yóò dé, ọwọ́ Olúwa sì níbẹ lára mi, o sì ya ẹnu mi ki ọkùnrin náà tó wá sọ́dọ̀ mi sílẹ̀ èmi kò sì lè dákẹ́ mọ́ Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn tí ó ń gbé nínú ìparun ní ilẹ Ísírẹ́lì ń wí pé, Ábúráhámù jẹ́ ọkùnrin kan, síbẹ̀ o gba ilẹ̀ ìní náà Ṣùgbọ́n àwa pọ̀ Lóòótọ́ a ti fi ilẹ̀ náà fún wa gẹ́gẹ́ bí ìní wa Nítorí náà sọ fún wọn pé, Èyí yìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin jẹ ẹ̀ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ni inú rẹ̀, tí ẹ̀yin sì wó àwọn ère yín, tí ẹ sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà Ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé idà yín, ẹ̀yin ṣe nǹkan ìríra, ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú yín baa obìnrin aládúgbò rẹ̀ jẹ́ Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà Sọ èyí fún wọn Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Bí mo ti wà láààyè, àwọn tí ó kúrò nínú ìparun yóò ti ipa idà ṣubú, àwọn tí ẹranko búburú yóò pajẹ, àwọn tí ó sì wà ní ilé ìsọ àti inú ihò òkúta ni àjàkálẹ̀-àrùn yóò pa Èmi yóò mú kí ilẹ náà di ahoro, agbára ìgbéraga rẹ̀ yóò sì di ahoro kí ẹnikẹ́ni má ṣe ré wọn kọjá Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa , nígbà tí mo bá mú ilẹ̀ náà di ahoro nítorí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ti ṣe Ní tìrẹ, ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn ìlú n sọ̀rọ̀ nípa rẹ ní ẹ̀gbẹ́ ògiri àti ní ẹnu ọ̀nà ilé wọn, wọ́n ń sọ sí ara wọn wí pé, Ẹ wá gbọ́ iṣẹ́ ti a ran láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá Àwọn ènìyàn mi wá sọ́dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe ń ṣe, wọn sì jòkòó níwájú rẹ láti fetísí ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò mú wá sí ìṣe Ẹnu wọn ní wọ́n fí n sọ̀rọ̀ ìfọkànsìn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn ní ìwọra èrè tí kò tọ́ Nítòótọ́ lójú wọn, ìwọ jẹ́ ẹni kan tí ó ń kọrin ìfẹ́ pẹ̀lú ohun dídara àti ohun èlò orin kíkọ, nítorí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ṣùgbọ́n wọn kò mu wá sí ìṣe Nígbà tí gbogbo ìwọ̀nyí bá ṣẹ tí yóò sì ṣẹ dandan, nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan ti wa láàárin wọn rí Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Àti Àgùntàn Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ mi wá Ọmọ ènìyàn, fí àsọtẹ́lẹ̀ tako olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ fún wọn pé Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ègbé ni fún olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì tí ó ń tọ́jú ara wọn nìkan! Ṣé ó dára kí olùṣọ́ àgùntàn ṣaláì tọ́jú agbo ẹran Ìwọ jẹ wàrà O sì wọ aṣọ olówùú sí ara rẹ, o sì ń pa ẹran tí ó wù ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò tọ́jú agbo ẹran Ìwọ kò ì tíì mú aláìlágbára lára le tàbí wo aláìsàn sàn tàbí di ọgbẹ́ fún ẹni tí o fi ara pa Ìwọ kò í tíì mú aṣàko padà tàbí wá ẹni tí ó nù Ìwọ ṣe àkóso wọn ní ọ̀nà lílé pẹ̀lú ìwà òǹrorò Nítorí náà wọn fọ́n káàkiri nítorí àìsí olùsọ́ àgùntàn, nígbà tí wọ́n fọ́n ká tán wọn di ìjẹ fún gbogbo ẹranko búburú Àgùntàn mi n rin ìrìn àrè kiri ní gbogbo àwọn òkè gíga àti òkè kékeré A fọ́n wọn ká gbogbo orí ilẹ̀ ẹni kankan kò sì wá wọn  Nítorí náà, ìwọ olùṣọ́ àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, nitorí pé agbo ẹran mi kò ní olùṣọ́ àgùntàn nítorí tí a kọ̀ wọ́n, tì wọ́n sì di ìjẹ fún ẹranko búburú gbogbo àti pé, nítorí tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn mi kò ṣe awárí agbo ẹran mi, ṣùgbọ́n wọn ń ṣe ìtọ́jú ara wọn dípò ìtọ́jú agbo ẹran mi, nítorí náà, ẹyin olùsọ́ àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi ṣe ìlòdì sí àwọn olùsọ́ àgùntàn, èmi yóò sì bèèrè agbo ẹran mi lọ́wọ́ wọn Èmi yóò sì mú wọn dẹ́kun àti máa darí agbo ẹran mi, tí àwọn olùsọ́ àgùntàn náà kò sì ní lè bọ́ ara wọn mọ́ Èmi yóò gba agbo ẹran mi kúrò ni ẹnu wọn, kì yóò sì jẹ́ oúnjẹ fún wọn mọ́  Nítorí èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi fúnra mi yóò wá àgùntàn mi kiri, èmi yóò sì ṣe àwárí wọn Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe fojú tó agbo ẹran rẹ̀ tí ó fọ́n ká nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò se fojú tó àgùntàn mi Èmi yóò gbá wọn kúrò ni gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n ká sí ni ọjọ ìkúukùu àti òkùnkùn Èmi yóò mú wọn jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì kó wọn jọ láti inú àwọn ìlú, èmi yóò sì mú wọn wá sí ilẹ ara wọn Èmi yóò mú wọn jẹ ni orí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì, ni àárin àwọn òkè àti ní gbogbo ibùdó ilẹ̀ náà Èmi yóò ṣe ìtọ́jú wọn ní pápá oko tútù dáradára, àní orí àwọn òkè gíga ti Ísírẹ́lì ni yóò jẹ́ ilẹ̀ ìjẹ koríko wọ́n Níbẹ̀ wọn yóò dùbúlẹ̀ ní ilẹ ìjẹ koríko dídára, níbẹ̀ wọn yóò jẹun ní pápá oko tútù tí ó dara ní orí òkè ti Ísírẹ́lì Èmi fúnra mi yóò darí àgùntàn mi, èmi yóò mú wọn dùbúlẹ̀, ni Olúwa Ọlọ́run wí Èmi yóò ṣe àwárí àwọn tí ó nú, èmi yóò mú àwọn tí ó ń rin ìrìn àrè kiri padà Èmi yóò di ọgbẹ́ àwọn tí ó farapa, èmi yóò sì fún àwọn aláìlágbára ni okun, ṣùgbọ́n àwọn tí ó sanra tí ó sì ni agbára ní èmi yóò parun Èmi yóò ṣe olùsọ́ àwọn agbo ẹran náà pẹ̀lú òdodo  Ní tìrẹ, agbo ẹran mi, èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrin àgùntàn kan àti òmíràn, àti láàrin àgbò àti ewúrẹ́ Ṣé oúnjẹ jíjẹ ní pápá oko tútù dídára kò tó yín! Ṣé ó jẹ́ dandan fún ọ láti fi ẹsẹ̀ tẹ pápá oko tútù rẹ tí ó kù Ṣé omi tí ó tòrò kò tó fún yín ní mímu Ṣe dandan ni kí ó fi ẹrẹ̀ yí ẹsẹ̀ yín Ṣé dandan ni kí agbo ẹran mi jẹ́ koríko tí ẹ ti tẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọn sì mú omi tí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ wọn sọ di ẹrẹ̀  Nítorí náà, èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí fún wọn Wòó, èmi fúnra mi yóò ṣe ìdájọ́ láàárin àgùntàn tí ó sanra àti èyí tí ó rù Nítorí ti ìwọ sún síwájú pẹ̀lú ìhà àti èjìká, tí ìwọ sì kan aláìlágbára àgùntàn pẹ̀lú ìwo rẹ títí ìwọ fi lé wọn lọ, Èmi yóò gba agbo ẹran mi là, a kì yóò sì kò wọ́n tì mọ́ Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrin àgùntàn kan àti òmíràn Èmi yóò fi olùsọ́ àgùntàn kan ṣe olórí wọn, ìránṣẹ́ mi Dáfídì, oun yóò sì tọ́jú wọn Òun yóò bọ́ wọn yóò sì jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn wọn Èmi Olúwa yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ìránṣẹ́ mi Dáfídì yóò jẹ́ ọmọ aládé láàárin wọn Èmi Olúwa ní o sọ̀rọ̀  Èmi yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn, èmi yóò sì gba ilẹ̀ náà kúrò lọ́wọ́ ẹranko búburú, kí wọn kí o lè gbé ní aṣálẹ̀, kí àgùntàn sì gbé ní inú igbó ní àìléwu Èmi yóò bùkún wọn àti ibi agbègbè ti ó yí òkè mi ká Èmi yóò rán ọ̀wààrà òjò ni àkókò òjò ìbùkún yóò sì wà Àwọn igi ìgbẹ́ yóò mú èso wọn jáde, ilẹ̀ yóò sì mu irúgbìn jáde A óò sì dá ààbò bo àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ náà Wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa , nígbà tí mo bá já àwọn ohun tí ó ṣe okùnfà àjàgà, tí mo sì gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó fi wọ́n ṣe ẹrú Àwọn orílẹ̀ èdè kì yóò lè kó wọn ní ẹrú mọ́, àwọn ẹranko búburú kì yóò lè pa wọn mọ́ Wọn yóò gbé ni àìléwu, kò sì sí ẹni kankan tí yóò le dẹ́rù bà wọ́n Èmi yóò pèsè ilẹ̀ ti o ní oríyìn fún èso rẹ̀ fún wọn, wọn kì yóò sì jìyà nípasẹ̀ ìyàn mọ́ ni ilẹ̀ náà tàbí ru ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀ èdè Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, èmi wà pẹ̀lú wọn àti pé, àwọn ilé Ísírẹ́lì jẹ́ ènìyàn mi, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ìwọ àgùntàn mi, àgùntàn pápá mi ni ènìyàn, èmi sì ni Ọlọ́run rẹ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí   Àsọtẹ́lẹ̀ Édómù Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn kọjú sí òkè Séírì ṣọtẹ́lẹ̀ síi Kí o sì sọ wí pé Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmí lòdì sí ọ, òkè Séírì, Èmi yóò sì na ọwọ́ mi síta ní ìlòdì sí ọ, èmi yóò sì mú kí o di ahoro Èmì yóò pa àwọn ìlú rẹ run, ìwọ yóò sì di ahoro Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa  Nítorí ìwọ dá ààbò bo ọ̀tẹ̀ àtayébáyé, tí ìwọ sì fi Ísírẹ́lì lé idà lọ́wọ́, ní àsìkò ìdààmú wọn, ní àsìkò tí ìjìyà wọn dé góńgó, nítorí náà bi mo ti wà láàyè, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, èmi yóò fi ọ kalẹ̀ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ Níwọ̀n ìgbà tí ìwọ kò ti korìíra ìtàjẹ̀-sílẹ̀, ìtàjẹ̀-sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ Èmi yóò mú kí òkè Séírì di ahoro ọ̀fọ̀ gbogbo àwọn tí ó ńlọ tí ó ń bọ̀ ní èmi yóò gé kúrò lára rẹ Èmi yóò fi àwọn tí a pa kún orí òkè rẹ àwọn tí a fi idà pa yóò ṣubú ní orí òkè rẹ, àti ní àárin àwọn òkè rẹ Èmi yóò mú kí o di ahoro títí láé Kò ní sí olùgbé ní ìlú rẹ Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa  Nítorí tí ìwọ sọ pé, Àwọn orílẹ̀ èdè àti ilẹ̀ méjì wọ̀nyí yóò jẹ́ tiwa, àwa yóò sì gbà wọ́n ní ìní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi Olúwa wà níbẹ̀, nítorí náà níwọ̀n ìgbà tí mo ti wà láàyè, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, èmi yóò hùwà sí ọ ní ìbámu pẹ̀lú ìbínú àti owú tí o fihàn nínú ìkórìíra rẹ sí wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ní àárin wọn, nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ rẹ Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti gbọ gbogbo ohun ẹ̀gàn tí ìwọ ti sọ lòdì sí àwọn òkè Ísírẹ́lì náà Ìwọ wí pé, A ti fi wọ́n sílẹ̀ ní ṣíṣọ̀fọ̀, a sì fi fún wa láti pajẹ Ìwọ lérí sí mi, ó sì sọ̀rọ̀ lòdì sí mí láìsí ìdádúró, èmi sì gbọ́ ọ Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Nígbà tí gbogbo ayé bá ń yọ̀, èmi yóò mú kí ó di ahoro Nítorí pé ìwọ ń yọ̀ nígbà tí ìní ilé Ísírẹ́lì di ahoro, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èmi yóò ṣe hùwà sí ọ Ìwọ yóò di ahoro, ìwọ òkè Séírì, ìwọ àti gbogbo ará Édómù Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa   Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Sí Àwọn Òkè Ísírẹ́lì Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ sí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì kí o sì wí pé, Ẹ̀yin òkè gíga Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Àwọn ọ̀tá sọ nípa yín pé, Áà! Àwọn ibi gíga ìgbàanì ti di ohun ìní wa   Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Nítorí pé wọn sọ ọ di ahoro, tí wọn sì ń dọdẹ rẹ ní gbogbo ọ̀nà kí ìwọ kí ó lè di ìní fún àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù, àti ohun ti àwọn ènìyàn ń sọ ọ̀rọ̀ ìríra àti ìdibàjẹ́ sí, nítorí náà, Ẹ̀yin òkè gíga Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun Èyí yìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí fún àwọn òkè gíga àti àwọn òkè kékèké, fún àfonífojì ńlá àti àfonífojì kékèké, fún àwọn ibi ìsọdahoro ìparun àti fún àwọn ìlú tí a ti kọ̀ sílẹ̀ tí a ti kó tí àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù ní àyíká sì fi ṣe ẹlẹ́yà Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ lòdì sí Édómù, nítorí pẹ̀lú ayọ̀ àti ìyodì ní ọkàn wọn ní wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀ Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì náà kí o sì sọ sí àwọn òkè gíga náà àti àwọn òkè kékèké, sí àwọn àfonífojì ńlá àti sí àwọn àfonífojì kéékèèkéé Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi sọ̀rọ̀ nínú ìrunú owú mi nítorí pé ìwọ ti jìyà ìfiṣẹ̀sín àwọn orílẹ̀ èdè Nítorí náà, Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé àwọn orílẹ̀ èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín  Ṣùgbọ́n ìwọ, òkè gíga Ísírẹ́lì, yóò mú ẹ̀ka àti èso fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, nítorí wọn yóò wá sílé ní àìpẹ́ yìí Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́ àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́, èmi yóò sì sọ iye àwọn ènìyàn di púpọ̀ nínú rẹ àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì Àwọn ìlú yóò di ibùgbé, a óò sì tún àwọn ibi ìparun kọ́ Èmi yóò sọ iye ènìyàn àti ẹran dì púpọ̀ nínú yín, wọn yóò sì so èso, wọn yóò sì di púpọ yanturu Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn máa gbé nínú rẹ bí ti àtẹ̀yìnwá, èmi yóò sì mú kí o ṣe rere ju ìgbà àtijọ́ lọ Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ pé èmi ni Olúwa Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn, àní àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, rìn lórí rẹ̀ Wọn yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì di ogún ìní wọn ìwọ kì yóò sì gba àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ wọn mọ́  Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Nítorí pé àwọn ènìyàn sọ fún ọ pé, Ìwọ pa àwọn ènìyàn run, ìwọ sì gba àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè lọ́wọ́ wọn, nítorí náà ìwọ kì yóò pa àwọn ènìyàn run tàbí mú kì orílẹ̀ èdè di aláìlọ́mọ mọ́, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi kì yóò mú ki ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè mọ́, ìwọ kì yóò jìyà ọ̀rọ̀ ìfiṣẹ̀sín láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tàbí mú kí orílẹ̀ èdè rẹ ṣubú, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí   Síwájú síi ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, nígbà tí àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ń gbé ní ilẹ̀ wọn, wọ́n bà á jẹ́ nípa ìwà àti ìṣe wọn Ìwà wọn dàbí nǹkan àkókò àwọn obìnrin ni ojú mi Nítorí náà mo tú ìbínú mi jáde sórí wọn nítorí wọn ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ti fi ère wọn ba a jẹ́ Mo tú wọn ká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, a sì fọ́n wọn ká sí àwọn ìlú mo ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti ìṣe wọn Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Olúwa , síbẹ̀ wọn ní láti fí ilẹ̀ náà sílẹ̀ Orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mi lógún, èyí tí ilé Ísírẹ́lì sọ di aláìmọ́ ni àárin àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti lọ Nítorí náà, sọ fún ilé Ísírẹ́lì, Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Kì í ṣe nítorí rẹ, ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ni èmi yóò ṣe ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí ti ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti lọ Èmi yóò fi jíjẹ́ mímọ́ orúkọ ńlá mi, èyí tí a ti sọ di aláìmọ́ hàn ni àárin àwọn orílẹ̀ èdè, orúkọ tí ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ni àárin wọn Nígbà náà àwọn orílẹ̀ èdè yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa , ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, nígbà tí mo bá fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ yín ni iwájú wọn  Nítorí èmi yóò mú yín jáde kúrò ni àwọn orílẹ̀ èdè náà Èmi yóò ṣà yín jọ kúrò ní gbogbo àwọn ìlú náà Èmi yóò sì mú yín padà sí ilẹ̀ ẹ̀yin tìkarayín Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára ẹ̀yin yóò sì mọ́ Èmi yóò sì fọ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìwà èérí yin gbogbo àti kúrò nínú gbogbo òrìṣà yin Èmi yóò fún yín ni ọkàn tuntun, èmi yóò sì fi ẹmi tuntun sínú yín Èmi yóò sì mú ọkàn òkúta kúrò nínú yín, èmi yóò sì fi ọkàn ẹran fún yín Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, èmi yóò sì mú ki ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ẹ sì fiyèsí àti pa òfin mi mọ́ Ẹ̀yin yóò sì máa gbé ilẹ̀ náà tí mo ti fi fún àwọn baba ńlá yín ẹyin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín Èmi yóò sì gbà yín kúrò nínú gbogbo ìwà àìmọ̀ yín Èmi yóò pèsè ọkà, èmi yóò sì mú kí ó pọ̀ yanturu, èmi kì yóò sì mú ìyàn wá sí orí yín Èmi yóò sọ èso àwọn igi yín àti ohun ọ̀gbìn oko yín di púpọ̀, nítorí kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jìyà ìdójútì mọ́ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè náà nítorí ìyàn Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rántí àwọn ọ̀nà búburú àti àwọn ìwà ìkà yín, ẹ̀yin yóò sì korìíra ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ìwà tí kò bójúmu Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì!  Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ iwólulẹ̀ ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́ Wọn yóò sọ wí pé, Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ṣíṣòfo tẹ́lẹ̀ ti dà bí ọgbà Édẹ́nì àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsìnyí Nígbà náà àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà ní àyíká yín tí ó kù yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti tún àwọn ohun tí ó bàjẹ́ kọ́, mo sì ti tún ohun tí ó di ìṣòfò gbìn Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi yóò sì ṣe e Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò yí sí ilé Ísírẹ́lì, èmi yóò sì ṣe èyí fún wọn Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn yín pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí àgùntàn, Kí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran fún ìrúbọ ní Jérúsálẹ́mù ní àsìkò àjọ Ìlú ti a parun yóò wá kún fún agbo àwọn ènìyàn Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Àfonífojì Àwọn Egungun Gbígbẹ Ọwọ́ Olúwa wà lára mi, ó sì mú mi jáde pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa , ó mú kí ń wà ní àárin àfonífojì ti o kún fún àwọn egungun Ó mú mi lọ síwájú àti sẹ́yìn láàrin wọn, èmi sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn egungun ní orí ilẹ̀ àfonífojì, àwọn egungun tí ó gbẹ gan Olúwa sì bi mí léèrè, Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ àwọn egungun wọ̀nyí lè yípadà di àwọn ènìyàn bí Èmi sì wí pé, Ìwọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìwọ nìkan ni o lè dáhùn sí ìbéèrè yìí Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, Ṣọtẹ́lẹ̀ sí àwọn egungun kí ó sì sọ fún wọn pé, Ẹ̀yin egungun gbígbẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ! Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí fún àwọn egungun wọ̀nyí Èmi yóò mú kí èémí wọ inú yín ẹ̀yin yóò sì wá di ààyè Èmi yóò so ìṣan ara mọ́ ọn yín, èmi yóò sì mú kí ẹran ara wá sí ara yín, èmi yóò sì fi awọ ara bò yín Èmi yóò sì fi èémí sínú yín, ẹ̀yin yóò sì wà ní ààyè Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa   Nítorí náà ni mo ṣe ṣọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ fún mi Bí mo sì ti ń ṣọtẹ́lẹ̀, ariwo wá, ìró tí ó kígbe sókè, àwọn egungun sì wà papọ̀, egungun sí egungun Mo wò ó, ìṣan ara àti ẹran ara farahàn lára wọn, awọ ara sì bò wọ́n, ṣùgbọ́n kò sí èémí nínú wọn Lẹ́yìn náà ni ó ṣọ fún mi pé, Ṣọtẹ́lẹ̀ sí èémí ṣọtẹ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn, kí ó sì ṣọ fún un pé, Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí wá láti atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìwọ èémí, kí ó sì mí èémí sínú àwọn tí a pa wọ̀nyí, kí wọn kí ó lè wà ní ààyè   Nítorí náà, mo ṣọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pa á láṣẹ fún mi, èémí sì wọ inú wọn Wọ́n di alààyè, wọ́n sì dìde dúró lórí ẹṣẹ̀ wọn—pẹ̀lú ìhámọ́ra tí ó pọ̀ Lẹ́yìn náà ó ṣọ fún mi Ọmọ ènìyàn, àwọn egungun wọ̀nyí ni gbogbo ìdílé Ísírẹ́lì Wọ́n ṣọ wí pé, Egungun wa ti gbẹ ìrètí wa sì ti lọ a ti gé wa kúrò Nítorí náà ṣọtẹ́lẹ̀, kí o sì ṣọ fun wọn pé, Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ Ẹ̀yin ènìyàn mi, Èmi yóò sí àwọn ibojì yín, èmi yóò sì mú yín wá si ilẹ̀ Isírẹ́lì Ẹ̀yin o sì mọ̀ èmi ni Olúwa , nígbà tí èmi bá ti sí bojì yín, ẹ̀yin ènìyàn mi, ti èmi bá si mú un yín dìde kúrò nińú bojì yín Èmi yóò fi èémí mi sínú yín, ẹ̀yin yóò sì yè, èmi yóò sì mú kí ẹ fi lélẹ̀ ní ilẹ̀ ẹ̀yín tìkára yín Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ti ṣọ̀rọ̀, èmi sì ti ṣe ni Olúwa wí   Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá Ọmọ ènìyàn, mú igi pátakó kan kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, Tí ó jẹ́ ti Júdà àti ti Ísírẹ́lì tí ó ní àsṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ Lẹ́yìn náà, kí ó mú igi pátakó mìíràn kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, Igi tí Éfúraímù jẹ́ ti Jósẹ́fù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tí ó ni àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ So wọ́n papọ̀ sí ara igi kan nítorí náà wọn yóò di ọ̀kan ní ọwọ́ rẹ Nígbà tí àwọn ara ìlú rẹ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, Ṣé ìwọ kò ní sọ ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wa Ṣọ fún wọn pé, Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi yóò gba igi Jósẹ́fù—èyí tí ó wà ní ọwọ́ Éfúráímù—àti ti ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí ó parapọ̀ mọ́ ọn, kí ó sì só papọ̀ mọ́ igi Júdà, láti sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo, wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi Gbé igi pátakó tí ó kọ nǹkan síi sókè ní iwájú wọn, kí ó sì sọ fún wọn pé, Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi yóò mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti lọ Èmi yóò ṣà wọ́n jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ ara wọn Èmi yóò ṣe wọ́n ní orílẹ̀ èdè kan ní ilẹ̀ náà, ní orí òkè Ísírẹ́lì, Ọba kan ni yóò wà lórí gbogbo wọn, wọn kì yóò sì jẹ́ orílẹ̀ èdè méjì mọ́, tàbí kí a pín wọn sí ìjọba méjì Wọn kì yóò sì tún fi àwọn òrìṣà wọn ba ara wọn jẹ́ mọ́, tàbí ohun ìríra wọn, tàbí ohun ìrékọjá wọn ṣùgbọ́n èmi yóò gbà wọn là kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgàbàgebè wọn, èmi yóò sì wẹ̀ wọn mọ́ Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn  Dáfídì ìránṣẹ́ mi ni yóò jẹ Ọba lórí wọn, gbogbo wọn yóò sì ní olùṣọ àgùntàn kan Wọn yóò sì tẹ̀lé òfin mi, wọn yóò sì ṣe àníyàn láti pa àṣẹ mi mọ́ Wọn yóò gbé ní ilẹ̀ tí mo fún Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba yín ń gbé Àwọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn ni yóò máa gbé ibẹ̀ láéláé, Ìránṣẹ́ mi Dáfídì ni yóò jẹ́ ọmọ Aládé wọn láéláé Èmi yóò dá májẹ̀mu àlàáfíà pẹ̀lú wọn, yóò sì jẹ́ májẹ̀mu títí ayérayé Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, èmi yóò sì ṣọ wọ́n di púpọ̀ ní iye, èmi yóò sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ ní àárin wọn títí láé Ibùgbé mí yóò wà pẹ̀lú wọn, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀ èdè yóò mọ̀ pé, èmi Olúwa ṣọ Ísírẹ́lì di mímọ́, nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà ní àárin wọn títí ayérayé   Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Sí Gógì Ọrọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí Gógì, ti ilẹ̀ Mágógì olórí Roṣi, Méṣékì, àti Túbálì ṣọtẹ́lẹ̀ ní ìlòdì sí i kí ó sì wí pé Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi lòdì sí ọ, Ìwọ Gógì, olórí ọmọ Aládé Méṣékì àti Túbálì Èmi yóò yí ọ kiri, èmi yóò sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní ẹnu, èmi yóò sì fà ọ́ jáde pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ, àwọn ẹṣin àti àwọn agẹsinjagun nínú ìhámọ́ra, àti ìpéjọ ńlá pẹ̀lú asà ogun ńlá àti kéékèèkéé, gbogbo wọn ń fi idà wọn Páṣíà, Kúsì àti Pútì yóò wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn yóò wà pẹ̀lú asà àti ìsíborí wọn Gómérì náà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àti Bẹti-Tógárímà láti jìnnàjìnnà àríwá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ̀-ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ̀  Múra sílẹ̀, múra tán, kí ìwọ àti gbogbo ìjọ náà péjọpọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí o sì pàṣẹ fún wọn Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àwa yóò pè ọ́ fún àwọn ohun èlò ogun Ní àwọn ọdún ọjọ́ iwájú ìwọ yóò dóti ilẹ̀ tí a ti gbà nígbà ogun, tí àwọn ènìyàn wọn kórajọ pọ̀ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè sí àwọn òkè gíga ti Ísírẹ́lì, tí ó ti di ahoro fún ìgbà pípẹ́ A ti mú wọn jáde láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè, nísínsínyìí gbogbo wọn ń gbé ní àìléwu Ìwọ àti ọ̀wọ́ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ yóò gòkè, ẹ̀yin yóò tẹ̀ṣíwájú bí ìjì ìwọ yóò dàbí ìkùùkuu tí ó bo ìlẹ̀ mọ́lẹ̀  Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ní ọjọ́ náà èrò kan yóò wá ṣọ́kan rẹ, ìwọ yóò sì pète ìlànà búbúru Ìwọ yóò wí pé, Èmi yóò gbé Ogun ti ilẹ̀ àwọn tí a kò fi odi yíká Èmi yóò gbé ogun ti àwọn ènìyàn àlàáfíà tí a kò furasí-gbogbo wọn ń gbé ní àìsí odi, ní àìsí ẹnu ọ̀nà òde àti àsígbà Èmi yóò mú ohun ọdẹ, èmi yóò sì kó ìkógun, èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sí ibi ìwólulẹ̀ ti a ti tún kọ́, àwọn ènìyàn tí a kójọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè, tí ó ní ọrọ̀ nínú nǹkan ọ̀sìn àti ẹrú, tí ó ń gbé ní àárin gbùngbùn ilẹ̀ náà Ṣébà, Dédánì àti àwọn oníṣòwò Táṣíṣì àti gbogbo ìletò rẹ yóò sọ fún un yín pé, Ṣé ẹ̀yin wá fún ìkógun Ṣé ẹ̀yin ti kó àwọn ìjọ yín jọpọ̀ fún ìkógun, láti kó silífà àti wúrà lọ, láti kó nǹkan ọ̀sìn àti ẹrú àti láti gba ọ̀pọ̀ ìkógun   Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ kí ó sì ṣọ fún Gógì Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ní ọjọ́ náà, nígbà tí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì ń gbé ní àìléwu, ìwọ kì yóò ha ṣe àkíyèsí rẹ̀ Ìwọ yóò wá láti ààyè rẹ ní jìnnàjìnnà àríwá, ìwọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ, gbogbo wọn yóò sì gun ẹsìn ìjọ ńlá, jagunjagun alágbára Ìwọ yóò tẹ̀síwájú ní ìlòdì sí àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀ Ni àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ìwọ Gógì, èmi yóò mú ọ wá ní ìlòdì sí ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀ èdè lè mọ̀ mi nígbà tí mo bá fí ara hàn ni mímọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ojú wọn  Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ìwọ ha kọ́ ni mo ṣọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà ìṣáájú láti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi ti Ísírẹ́lì Ní ìgbà náà wọ́n ṣọtẹ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pé èmi yóò mú ọ lòdì sí wọn Èyí ni ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà Nígbà tí Gógì bá kọlu ilẹ̀ Ísírẹ́lì, gbígbóná ibínú mi yóò ru sókè, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ní ìtara mi àti ní gbígbóná ìbínú mi, Mo tẹnumọ́-ọn pé ní àsìkò náà ilẹ̀ mímì tíi ó lágbára ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì yóò ṣẹlẹ̀ Ẹja inú òkun, àwọn ẹyẹ òfuurufú, àwọn ẹranko igbó, àti gbogbo ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀ yóò wárìrì fún ìfarahàn mi A óò yí òkè gíga po, àwọn bèbè òkúta ni àwa yóò fọ́ sí wẹ́wẹ́, gbogbo ògiri ni yóò wó palẹ̀ Èmi yóò fa idà yọ ni ìlòdì sí Gógì ní orí gbogbo àwọn òkè gíga mi ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Idà gbogbo ènìyàn yóò lòdì sí arákùnrin rẹ̀ Èmi yóò gbé ìdájọ́ mi jáde lórí rẹ̀ pẹ̀lú ìyọnu àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ Èmi yóò dá àgbàrá òjò, òkúta yìnyín àti imí ọjọ́ tí ń jó lé e lórí àti lórí ọ̀wọ́ ogun àti lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ̀ Nítorí náà, Èmi yóò fi títóbi mi àti ìjẹ́-mímọ́ mi hàn, Èmi yóò sì fi ara mi hàn ní ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ sí Gógù, kí ó sì wí pé Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi lòdì sí ọ, Ìwọ Gógì, olórí ọmọ-aládé ti Mésékì àti Túbálì Èmi yóò dá ọ padà, èmi yóò sì darí rẹ Èmi yóò mú ọ wá láti jìnnàjìnnà ìhà àríwá, Èmi yóò rán ọ lòdì sí orí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì Nígbà náà èmi yóò lu ọrùn awọ rẹ ní ọwọ́ òsì rẹ, èmi yóò sì mú kí àwọn ọfà rẹ jábọ́ ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ Ìwọ yóò sì subú ní orí àwọn òkè Ísírẹ́lì, ìwọ àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ àti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà pẹ̀lú rẹ Èmi yóò fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn onírúurú ẹyẹ àti fún àwọn ẹranko igbó Iwọ yóò ṣubú ní gbangba pápá, nítorí tì mo ti sọ̀rọ̀, ni Olúwa Ọba wí Èmi yóò fi iná sí mágógì àti sí àwọn tí ń gbé ní agbègbè ilẹ̀ ibẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa  Èmi yóò sọ orúkọ mímọ́ mí di mí mọ̀ láàrin àwọn èniyàn mì Isìrẹli Èmi ki yóò jẹ́ kí orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́ àwọn orílẹ èdè yóò mọ̀ pé èmi Olúwa , èmi ni ẹni mímọ́ ní Ísírẹ́lì Ó ń bọ̀! Ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀, ni Olúwa Ọba tẹnumọ́ Èyi yìí ni ọjọ́ tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀  Nígbà náà, àwọn ti ó ń gbé nì àárin àwọn ìlú tí ó wà ni Ísírẹ́lì yóò jáde, wọn yóò sì lo àwọn ohun ìjà bi epo ìdáná yóò sì jó wọ́n kanlẹ—àpáta kékèké àti àpáta ńlá, àwọn ọfà, àwọn kùmọ̀ ogun àti ọ̀kọ̀ fún ọdún méje wọn yóò lò wọ́n bi epo ìdáná Wọn kò ní nílo láti kó igi jọ láti inú pápá, tàbí gé e láti inú igbó, nítorí pé wọ́n yóò lé òhun ìjà ogun bi epo ìdáná Wọn yóò sì kógun àwọn tí ó ṣe ìgárá sí wọn, wọn yóò sì bo ilé àwọn tí ó bo ilé wọn, ni Olúwa Ọba tẹnumọ́  Ní ọjọ́ náà èmi yóò sì fi ibi ìsìnkú fún Gógì ní Ísírẹ́lì, ni àfonífojì àwọn ti ó rìn ìrìnàjò lọ sí agbègbè ilà òòrùn òkun Yóò di ojú ọ̀nà àwọn arìnrìn àjò, nítorí Gógì àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni àwa yóò sin síbẹ̀ Nítorí náà, a óò pè é ní àfonífojì tí Ámónì Gógì  Fún oṣù méje ní ilé Ísírẹ́lì yóò fi máa sìn wọ́n láti ṣe àfọ̀mọ́ ilẹ̀ náà Gbogbo ènìyàn ilẹ náà yóò sìn wọ́n, ọjọ́ tí a yìn mi lógo yóò jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ní Olúwa Ọba wí  Wọn yóò gbà àwọn ènìyàn ṣíṣẹ́ lóòrèkóórè láti ṣe àfọ̀mọ́ náà Ọ̀pọ̀ yóò lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ní àfikún pẹ̀lú wọn, àwọn tó kù yóò sìn àwọn tí ó kú lórí ilẹ̀ Ní ìparí oṣù kéje wọn yóò bẹ̀rẹ̀ wíwá kiri wọn Bí wọ́n n lọ káàkiri ilẹ̀ náà ọ̀kan nínú wọn rí egungun ènìyàn, oun yóò gbé àmì ńlá kalẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ títí àwọn asìnkú yóò fi sìn ín ní àfonífojì Ámónì Gógì Nítorí náà wọn yóò wẹ ilẹ̀ náà Ọmọ ènìyàn èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọba wí pé pe gbogbo oríṣìíríṣìí ẹyẹ àti gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́ jáde kí wọn pé jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè sí ìrúbọ tí mó ń múra rẹ̀ fún ọ, ìrúbọ ńlá náà ní orí òkè gíga tí Ísírẹ́lì Níbẹ̀ ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ Ẹ̀yin yóò jẹ ẹran ara àwọn ènìyàn ńlá, ẹ o sì mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ aládé ayé bí ẹni pé wọn jẹ́ àgbò àti ọ̀dọ́ àgùntàn, ewúrẹ́ àti akọ màlúù gbogbo wọn jẹ́ ẹran Ọlọ́ràá láti Báṣánì Níbi ìrúbọ tí mo ń múra kalẹ̀ fún yín, ẹ̀yin yóò jẹ ọ̀rá títí ẹ̀yin yóò fi jẹ àjẹkì, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ títí ẹ̀yin yóò fi yó Ní orí tábìlì mi ni àwa yóò ti fi ẹṣin àti ẹlẹ́sin bọ yín yó, pẹ̀lú àwọn alágbára ńlá àti oríṣìríṣìí jagunjagun ni Olúwa Ọba sọ Èmi yóò ṣe àfihàn ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sì rí ìyà tí mo fi jẹ wọ́n Láti ọjọ́ náà lọ, ilé Ísírẹ́lì yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn Àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí mi Nítorí náà mo mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, mo sì fi wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, gbogbo wọn sì subú nípasẹ̀ idà Mo ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí àìmọ̀ àti àìṣedéédéé wọn, mo sì mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Ọba wí Èmi yóò mú Jákọ́bù padà kúrò ní oko ẹrú, èmi yóò ní iyọ́nú si gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì, èmi yóò sì ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi Wọn yóò gbàgbé ìtìjú wọn àti gbogbo àìsòdodo tí wọ́n fihàn sí mi nígbà tí wọn ń gbé ni àìléwu ni ilẹ̀ wọn níbi tí kò ti sí ẹnìkẹ́ni láti dẹ́rù bà wọ́n Nígbà tí mo ti mú wọn padà kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo sì kó wọn jọ pọ̀ kúrò ni ìlú àwọn ọ̀tá wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ wọn ní ojú àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀ Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo rán wọn lọ sí ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò kó wọn jọ sí orí ilẹ̀ wọn, láì fi ìkankan sẹ́yìn Èmi kì yóò sì fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn mọ nítorí èmi yóò tú èémí mi jáde sí ilé Ísírẹ́lì, ní Olúwa Ọba wí A Ya Àwòrán Ìgbóguntì Jérúsálẹ́mù Nísinsìnyìí, Ìwọ ọmọ ènìyàn, mú amọ̀ ṣíṣù kan, gbé e sí iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán Jérúsálẹ́mù sí orí rẹ̀ Kí o sì dó tì í, kí o sì mọ ilé ìṣọ́ tì í, kí o sì mọ odi tì í, kí o sì gbé ogun sí i, kí o sì to òòlù yí i ká Kí o sì fi páànù irin kan ṣe ògiri láàrin rẹ̀ àti ìlú yìí, dojú kọ ọ́, kí o sì gbógun tì í Èyí yóò jẹ́ àmì fún ilé Ísírẹ́lì Lẹ́yìn èyí, lọ fi ẹ̀gbẹ́ òsì dúbúlẹ̀, kí o sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì lé orí ara rẹ Iye ọjọ́ tí ìwọ bá fi sùn náà ni ìwọ yóò fi ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn Nítorí mo fi iye ọdún tí wọ́n fi ṣẹ̀ fún ọ gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ tí ìwọ yóò lò Nítorí náà, ìwọ yóò ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá Tí o bá parí èyí, tún fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ kí o sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Júdà fún ogójì ọjọ́, nítorí pé ọjọ́ kan ló dúró fún ọdún kan Dojú kọ ibùdó ogun Jérúsálẹ́mù, na ọwọ́ rẹ sí i, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú náà Èmi yóò dè ọ́ ní okùn débi pé ìwọ kò ní í le yírapadà láti ìhà ọ̀tún sí ìhà òsì títí tí ọjọ́ ìgbógun tì rẹ yóò fi pé Mú ọkà bàbà àti àlìkámà, erèé àti lẹ́ńtìlì, jéró àti ẹwẹ fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá Wọn òṣùnwọ̀n ogún ṣékélì oúnjẹ tí ìwọ yóò máa jẹ-lójoojúmọ́ kí o sì máa jẹ ẹ́ ní àkókò tí a ti yà sọ́tọ̀ Bákan náà, wọn ìdámẹ́fà hínì omi, kí ìwọ ó sì máa mú ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀ Ìwọ yóò sì jẹ ẹ́ bí àkàrà báálì dín in ní ojú àwọn ènìyàn, ìgbẹ́ ènìyàn ni kí o fi dáná rẹ Olúwa sọ pé, Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jẹ oúnjẹ àìmọ́ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí èmi yóò lé wọn lọ Nígbà náà ni mo wí pé, Áà! kò rí bẹ́ẹ̀ Olúwa Ọlọ́run! Láti ìgbà èwe mi di ìsinsìnyìí èmi kò tí ì sọ ara mi di aláìmọ́ rí Èmi kò tí ì jẹ ohun tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko búburú fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ Bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kan kò tí ì wọ ẹnu mi rí Nígbà náà ló wí fún mi pé, Wò ó, Èmi ó fún ọ ní ìgbẹ́ màlúù dípò ìgbẹ́ ènìyàn Èmi yóò mú ki ó dín àkàrà rẹ lórí ìgbẹ́ màlúù dípò igbẹ ènìyàn Ó sì tún sọ fún mi pé Ọmọ ènìyàn, èmi yóò dáwọ́ ìpèsè oúnjẹ dúró ní Jérúsálẹ́mù Ní pípín ni àwọn ènìyàn yóò máa pín oúnjẹ́ jẹ pẹ̀lú ìfọ̀kansọ́nà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wọn yóò máa mu omi pẹ̀lú ìdààmú, nítorí pé oúnjẹ àti omi yóò wọ́n Wọn yóò máa wo ara wọn pẹ̀lú ìyanu, èmi yóò sì jẹ́ kí wọ́n ṣọ̀fọ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn Agbégbé Tẹ́mpìlì Tuntun Ní ọdún kẹẹdọ́gbọ̀n tí a ti wà ni oko ẹrú wa, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún, ni oṣù kẹwàá ọdún kẹ́rinlá lẹ́yin ìsubú ìlú ńlá náà ní ọjọ́ náà gan an ọwọ́ Olúwa ń bẹ̀ lára mi, oùn sì mú mi lọ síbẹ̀ Nínú ìran Ọlọ́run, ó mú mí lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ó sì gbé mi lọ sí orí òkè gíga fíofío Ní ẹ̀gbẹ́ gúsù ọ̀pọ̀ ilé tó wà níbẹ̀ dàbí ìlú ńlá Ó mú mi lọ síbẹ̀, mo sì rí ọkùnrin kan tí ìrírí rẹ̀ dàbí ìrí bàba ó dúró ni ẹnu ọ̀nà pẹ̀lú okùn aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun àti ọ̀pá ìwọnlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, Ọmọ ènìyàn, wò pẹ̀lú ojú rẹ kí o sì gbọ́ pẹ̀lú etí rẹ, kí ó sì farabalẹ̀ sì gbogbo ohun tí mo máa fi hàn ọ, nítorí ìdí nìyí tí a fi mú ọ wá síhìn-ín Sọ gbogbo ohun tí ó bá rí fún ilé Ísírẹ́lì Mo rí ògiri tí ó yí agbègbè ibi mímọ̀ po Gígùn ọ̀pá ìwọnlẹ̀ tí ó wà ní ọwọ́ ọkùnrin náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà, ọkọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ilásì mẹ́rin ẹsẹ̀ bàtà Ó wọn ògiri náà ó jẹ́ ìwọ̀nyí ọ̀pá náà ni níní ipọn, ó sì jẹ́ ọ̀pá kan ní gíga Lẹ́yìn náà ni ó wá lọ sí ẹnu ọ̀nà òde tí ó kọjú sí ìlà òòrùn Ó gun àtẹ̀gùn rẹ̀, o sì wọn ìloro ẹnu ọ̀nà ilé ó jẹ́ ọ̀pa kan ní jíjìn Yàrá kéékèèkéé sì jẹ ọ̀pá kan ni gígùn àti ọpá kan ní ibú, ìgbéró ògiri àárin yàrá kéékèèkéé náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni nínípọn Ìloro ẹnu ọ̀nà náà tí ó kángun sí àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà náà tó kọjú sì tẹ́ḿpìlì jẹ́ ọ̀pá kan ní jíjìn Lẹ́yìn náà, ó wọn àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà Ó jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ ní jíjìn àtẹ́rígbà rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjì ní nínípọ̀n Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà kọjú sí tẹ́ḿpìlì Ní ẹnu ọ̀nà ìlà òòrùn ni àwọn yàrá kéékèèkéé mẹ́ta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kọ̀ jú sí ara wọn, ojú ìgbéró ògiri ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ bákan náà ní wíwọ̀n Lẹ́yìn náà ó wọn ìbú à bá wọ ẹnu ọ̀nà náà ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wà, gígùn rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́tàlá Ní iwájú ọ̀kọ̀ọ̀kan yàrá kéékèèkéé kọ̀ọ̀kan ní ògiri tí gíga rẹ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan wà, ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àwọn yàrá kéékèèkéé sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà Lẹ́yìn náà, ó wọn ẹnu ọ̀nà láti òkè ẹ̀yìn ògiri yàrá kéékèèkéé kan títí dé òkè àdojúkọ ọ̀kan jínjìn sí ara wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ́dọ́gbọ̀n láti odi kan tí ó sí sílẹ̀ sí àdojúkọ ọ̀kan Ó wọ̀n ọ́n lọ sí àwọn ojú àwọn ìgbéró ògiri gbogbo rẹ̀ yí inú òjú ọ̀nà ó jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́ Ìwọ̀n náà tó àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ àgbàlá Ìjìnà ẹnu ọ̀nà àbáwọlé títí dé ìparí yàrá kéékèèkéé náà àti àwọn ìgbéró ògiri nínú ẹnu ọ̀nà ní a gbé dá jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ Ni a tẹ nínú yíká àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ní fèrèsé tóóró tí ó wọ inú yíká Awọn ògiri wọn ní inú ni a fi pákó tẹ yíká láti ilẹ̀ dé òkè fèrèsé ati láti fèrèsé dé òrùlé Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ojú òde àgbàlá Níbẹ̀ mo rí yàrá díẹ̀ àti pèpéle tí a kọ́ yí àgbàlá ká ọgbọ̀n yàrá wà lẹ́gbẹ̀ pèpéle náà, O ṣe ààlà sí ẹ̀gbẹ́ àwọn ẹnu ọ̀nà, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà pẹ̀lú gígun rẹ̀ èyí jẹ́ pèpéle tí ìsàlẹ̀ Lẹ́yìn náà, o wọn jíjìnna rẹ̀ láti inú ìsàlẹ̀ ẹnu ọ̀nà títí dé àgbàlá tí inú ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà òòrùn àti tí àríwá Lẹ́yìn náà, ó wọn gígùn àti ibú ẹnu ọ̀nà tí ó dojú kọ àríwá, à bá wọ àgbàlá Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀ mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà jẹ́ bákan náà ni wíwọ̀n gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́ Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni fífẹ̀ Ojú ihò rẹ̀, àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ àti igi ọ̀pẹ tí iṣe ọ̀sọ́ rẹ̀ ni wọn kàn gẹ́gẹ́ bí tí àwọn ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ ìlà òòrùn Àtẹ̀gùn méje ní ó dé ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà òdìkejì wọn Ẹnu ọ̀nà kan sí àgbàlá ti inú ni àdojúkọ ẹnu ọ̀nà àríwá, gẹ́gẹ́ bí o ṣe wà ní ìlà òòrùn Ó wọ̀n láti ẹnu ọ̀nà sí àdojúkọ ọ̀kan ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí ìhà gúsù, mo sì rí ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ gúsù Ó wọn àtẹ́rígbà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà, wọ́n jẹ́ bákan náà bí ti àwọn tí o kù Ẹnu ọ̀nà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ni ojú ihò tóóró yí po, gẹ́gẹ́ bí ojú ihò ti àwọn tókù Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ní fífẹ̀ Àtẹ̀gùn méje ní ó dé ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ní òdì kejì wọn Ó ní igi ọ̀pẹ tí a fi ṣe ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ni ojú ìgbéró ògiri ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan Àgbàlá ti inú náà ní ẹnu ọ̀nà yìí sí ẹnu ọ̀nà ìta ni ìhà gúsù Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí àgbàlá ti inú láti ẹnu ọ̀nà gúsù, ó ní ìwọ̀n kan náà ẹnu ọ̀nà gúsù ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà jẹ́ bákan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù Ẹnu ọ̀nà náà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ní ihò ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gbogbo Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ tí ó dojúkọ àgbàlá tí ìta, igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀sọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó lọ sì òkè sí i Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí àgbàlá tí inú ni ìhà ilà òòrùn, ó sì wọn ẹnu ọ̀nà ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù Ẹnu ọ̀nà náà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ni ihò yí po Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ àgbàlá tí ìta àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀sọ́ sí àtẹ́rígbà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ sì lọ sókè rẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀ ṣe rí Àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà, ó sì ní àwọn ihò yí i po O jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dọgbọ̀n ní fífẹ̀ Àwọn yàrá ẹ̀sọ́ rẹ̀ àwọn òpó rẹ̀ àti ìloro rẹ̀, àti fèrèsé rẹ̀ yíká gígùn rẹ̀ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àti ìbú rẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ mẹẹdọ́gbọ̀n Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ àgbàlá ìta àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀sọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó so mọ́ ọn lókè Yàrá kan pẹ̀lú ilẹ̀kùn wà ní ẹ̀gbẹ́ àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ní ọ̀kọ́ọ́kan ẹnu ọ̀nà inú, níbi tí wọn tí ń fọ àwọn ẹbọ sísun Ní àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tí ẹnu ọ̀nà ni tẹ́ḿpìlì méjì wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan, lórí èyí tí a ti ń pá ọrẹ ẹbọ sísun, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ Ní ẹ̀gbẹ́ ògiri ìta àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà tí ẹnu ọ̀nà, tí ó súnmọ́ àwọn àtẹ̀gùn ní àbáwọlé tí ẹnu ọ̀nà àríwá ni tẹ́ḿpìlì méjì wà, ní ẹ̀gbẹ́ kejì tí àtẹ̀gùn ní tẹ́ḿpìlì méjì wà Nítorí náà, tẹ́ḿpìlì mẹ́rin ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan ẹnu ọ̀nà, mẹ́rin sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì tẹ́ḿpìlì, mẹ́jọ ni gbogbo rẹ̀ lórí èyí ni a ti ń pa ohun ìrúbọ Tẹ́ḿpìlì mẹ́rin tí à fi òkúta ṣe lọ́sọ̀ọ́ sì tún wà fún ẹbọ sísun, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ni gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ kan ni gíga Ní orí rẹ̀ ni a kó àwọn ohun èlò fún pípa, ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ìrubọ tí ó kù sí Ìlọ́po méjì ohun èlò bí àmúga tí o ní ìwọ̀ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìbú ọwọ́ ní gígùn, ni a so mọ́ ara ògiri yíká Àwọn tẹ́ḿpìlì náà wa fún ẹran ohun ìrúbọ Lẹ́yìn náà ó wọn àgbàlá Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ Pẹpẹ sì wà ní iwájú tẹ́ḿpìlì Ó sì wí fún mi pé, yàrá yìí, tí iwájú rẹ̀ wà níhà gúsù, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti n bojútó ilé náà Iyàrá ti iwájú rẹ̀ ti o wà níhà àríwá, wà fún àwọn àlúfáà, àwọn ti ń bojútó pẹpẹ náà, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Sádókù nínú àwọn ọmọ Léfì, tí wọ́n ń súnmọ́ Olúwa láti ṣe ìránṣẹ́ fún un Ó sì wọn àgbàlá náà, ọgọ́rùn ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọgọ́rùn ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú, igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, àti pẹpẹ ti ń bẹ níwájú ilé náà Ó mú mi lọ sí àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tẹ́ḿpìlì, ó sì wọn àwọn àtẹrígbà àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà wọ́n jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní fífẹ̀, ẹ̀gbẹ́ méjèèjì rẹ̀ Fífẹ̀ àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá, ìgbéró àwọn ògiri náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní fífẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ méjìlá láti iwájú dé ẹ̀yìn Láti ara àtẹ̀gùn ní a ti ń dé ibẹ̀ àwọn òpó sì wà ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àwọn àtẹ́rígbà náà Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi lọ sí ìta ibi mímọ́, ó sì wọn àwọn àtẹ́rígbà náà ìbú atẹrígbà náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní ègbẹ́ kọ̀ọ̀kan Ẹnu ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní fífẹ̀, ẹ̀gbẹ́ ògiri ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì Ó sì wọn ìta ibi mímọ́ bákan náà ó jẹ́ ogójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, o sì jẹ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ Lẹ́yìn náà ó lọ sí inú yàrá ibi mímọ́, ó sì wọn àtẹ́rígbà àbáwọlé ìkọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni fífẹ̀ Àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni fífẹ̀, ẹ̀gbẹ́ ògiri àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méje ni fífẹ̀ O sì wọn gígùn inú yàrá ibi mímọ́ o sì jẹ ogún ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ títí dé ìparí ìta ibi mímọ́ O sì sọ fún mi pé, Èyí yìí ni ibi mímọ́ jùlọ Lẹ́yìn náà ó wọn ògiri ilé Ọlọ́run náà ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní nínípọn, yàrá kọ̀ọ̀kan tí ó wà ńi ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ yípo ilé Ọlọ́run náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀ Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ wà ni ìpele mẹ́ta, lórí ara wọn, nígbà ọgbọ̀n lórí ìkọ̀ọ̀kan Àwọn arópòdógìri wà yípo ògiri ilé Ọlọ́run náà mú kí ògiri àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́gbẹ́ náà ní agbára, ni ọ̀nà tí àwọn ìfaratì náà kò fi wọ inú ògiri ilé Ọlọ́run náà lọ Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ yípo tẹ́ḿpìlì ń fẹ̀ sí i bí wọ́n ṣe ń lọ sí òkè sí i Àwọn ilé tí a kọ́ yípo ilé Ọlọ́run ni a kọ́ sókè ní pele ní pele, èyí mú kí àwọn yàrá yìí máa fẹ̀ sí i bí ó ṣe ń gòkè sí i Àtẹ̀gùn rẹ̀ gba ti àwùjọ ilé àárin lọ sókè láti ilé títí dé òkè pátapáta Mo ri i pé ilé Ọlọ́run náà ní ìgbásẹ̀ tí a mọ yí i ká, tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ ilé tí a mọ yí àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́gbẹ́ po Ó jẹ́ ìwọ̀n ọ̀pá náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní gígùn Ògiri ìta àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ni nínípọn Agbègbè tí ó wà lófo ní àárin àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ ilé Ọlọ́run náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún yípo Yàrá àwọn àlùfáà jẹ́ ogun ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ yí pó témpílì náà Àwọn ojú ọ̀nà àbáwọlé wá sí àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́, ọ̀kan ní àríwá àti èkejì ní gúsù, ojú ọ̀nà ni ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀wọ́ márùn-ún ní fífẹ̀ yípo rẹ̀ Ilé tí ó dojúkọ ìta gbangba ìṣèré ilé Ọlọ́run náà ní ìhà ìwọ̀ òòrùn jẹ́ àádọ́rin ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ Ògiri ilé náà nípọn tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún yípo, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ Lẹ́yìn èyí ní ó wá wọn ilé Ọlọ́run Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ìta gbangba ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ilé àti ògiri rẹ̀ náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn Ibú ìta gbangba ilé Ọlọ́run ní ìhà ìlà òòrùn, papọ̀ mọ́ iwájú ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ Ó wá wọn gígùn ilé tí ó dojúkọ gbangba ìta ní agbègbè ilé Ọlọ́run papọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ Ìta ibi mímọ́, inú ibi mímọ́ náà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ ìta gbangba, àti pẹ̀lú àwọn ìloro ilé àti àwọn fèrèsé tóóró pẹ̀lú ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè yípo àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, gbogbo rẹ̀ ní ìta papọ̀ mọ́ ìloro ilé ni wọ́n fi igi bò Ilẹ̀ ògiri sókè títí dé ojú fèrèsé ni wọ́n fi igi bò pátapáta Ní ìta gbangba lókè ìta ẹnu ọ̀nà inú ibi mímọ́ àti lára ògiri pẹ̀lú àlàfo tí kò ju ara wọn lọ yípo inú ìta ibi mímọ́ ní wọn fín àwọn kérúbù àti àwọn igi ọ̀pẹ Wọn fi àwọn igi ọ̀pẹ bo àárin àwọn kérúbù Kérúbù kọ̀ọ̀kan ní ojú méjìméjì Ojú ènìyàn sí ìhà igi ọ̀pẹ ni ẹ̀gbẹ́ kan, ojú ọ̀dọ́ kìnnìún sí ìhà igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ kejì Wọn fín gbogbo rẹ̀ yípo gbogbo ilé Ọlọ́run Láti ilẹ̀ sí agbègbè òkè ẹnu ọ̀nà, àwọn Kérúbù àti àwọn igi ọ̀pẹ ni wọ́n fín si ara ògiri ìta ibi mímọ́ Ìta ibi mímọ́ ni férémù onígun mẹ́rin pẹ̀lú ìkan tí ó wà ní ibi mímọ́ jùlọ rí bákan náà Pẹpẹ ìrúbọ kan tí a fi igi ṣe wà, gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, àwọn igun rẹ̀, ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti ògiri rẹ́ jẹ́ igi Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, Èyí yìí ní tẹ́ḿpìlì tí ó wà ní iwájú Olúwa Ìta ibi mímọ́ àti ibi mímọ́ jùlọ ni ilẹ̀kùn méjì papọ̀ Lẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan ní ewé méjìméjì, ewé méjì tí a gbe kọ́ fún ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan Ní ẹnu ilẹ̀kùn ní ìta ibi mímọ́ ni àwọn kérúbù àti igi ọ̀pẹ tí a fín bí ti àwọn tí a fín si àwọn ara ògiri, ìbòrí tí á fí igi ṣe wà ní iwájú ẹnu ọ̀nà ilé ní ìta Ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ògiri ẹnu ọ̀nà ní àwọn fèrèsé tóóró pẹ̀lú igi ọ̀pẹ tí a fín ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì wà Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ilé Ọlọ́run náà ni ìbòrí tí a fi igi ṣe Àwọn Yàrá fún Àwọn Àlùfáà Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ìta gbangba ni ìhà àríwá ó sì mú mi wọ àwọn yàrá ni òdìkejì ìta gbangba ilé Ọlọ́run àti ni òdìkejì ogiri ìta ní apá ìhà àríwá Ilé tí ilèkùn rẹ̀ kọjú sí àríwá jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó sì jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ Méjèèjì ní ogún ìgbọ̀nwọ́ ìpín láti inú ilé ìdájọ́ àti ni ìpín tí ó dojúkọ iwájú ìta ìdájọ́, ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè kọjú sì ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè ní ìdọ́gba mẹ́ta Ní iwájú àwọn ọ̀nà, yàrá wà nínú tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní fífẹ̀ tí ó sì jẹ́ ọgọ́ọrùn ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn Àwọn ilẹ̀kùn wọn wà ní apá ìhà àríwá Nísinsìn yìí àwọn yàrá òkè ṣe tóóró, nítorí ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè dàbí ẹni pé ó ní ààyè láti ara wọn ju láti ara àwọn yàrá ti ó wà ní ìsàlẹ̀ tàbí àárin ilé Àwọn yàrá tí ó wà ní àgbékà kẹta kò ni àwọn òpó gẹ́gẹ́ bí ilé ìdájọ́ ṣe ní nítorí náà wọ́n kéré ni níní ààyè ju àwọn tí ó wà ní ìsàlẹ̀ àti àwọn àgbékà ti àárin Ògiri kan wà ní ìta tí ó ṣe déédé pẹ̀lú àwọn yàrá àti ìta ilé ìdájọ́ a fàá gùn ní iwájú àwọn yàrá ní àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ Nígbà tí ọ̀wọ́ yàrá ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kángun sí ìta ilé ìdájọ́ jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọ̀wọ́ ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ tí ó sún mọ́ ibi mímọ́ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn Yàrá ìsàlẹ̀ ni ẹnu ọ̀nà ní ìhà ìlà oòrùn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ṣe wọ inú rẹ̀ láti ìta ilé ìdájọ́ Ní ìhà gúsù lọ sí ìbú ògiri ìta ilé ìdájọ́ tí o ṣe déédé pẹ̀lú àgbàlá ilé Ọlọ́run, ní òdìkejì ògiri ìta ni àwọn yàrá náà wà Àti ọ̀nà ni iwájú wọn rí gẹ́gẹ́ bí ti ìrí àwọn yàrá tí ó wà ní ọ̀nà àríwá bí wọ́n ti gùn mọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbòòrò mọ àti gbogbo ìjáde wọn sì dàbí ìṣe wọn àti bí ìlẹ̀kùn wọn bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní yàrá tí òun ti ìlẹ̀kùn wọn ní ọ̀nà gúsù, ìlẹ̀kùn kan wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ojú ọ̀nà tí ó ṣe déédé pẹ̀lú ògiri tí ó gùn dé ìhà ìlà oòrùn tí ènìyàn ń gba wọ inú àwọn yàrá Ó sì wí fún mi pé, Àwọn yàrá àríwá àti àwọn yàrá gúsù, tí ó wà níwájú ibi tí a yà sọ́tọ̀ àwọn ni yàrá mímọ́, níbi tí àwọn àlùfáà ti ń súnmọ́ Olúwa yó máa jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ níbẹ̀ ní wọn o máa gbé ohun mímọ́ jùlọ kà, àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá nítorí ibẹ̀ jẹ́ mímọ́ Ní wọ̀n ìgbà tí àwọn àlùfáà bá ti wọ aṣọ funfun ibi mímọ́, wọn kò gbọdọ̀ lọ sí ìta ilé ìdájọ́ àfi tí wọ́n bá bọ àwọn aṣọ tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ ìsin sílẹ̀ ní ibi tí wọn tí lò ó, nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́ Wọn gbọdọ̀ wọ aṣọ mìíràn kí wọn tó sún mọ́ ibi tí àwọn ènìyàn yòókù máa ń wà Nígbà tí o parí nǹkan tí ó wà nínú ilé Ọlọ́run tán, o mú mi jáde lọ sí ọ̀nà tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ó sì wọn agbégbé náà yípo Ó wọn ìhà ìlà oòrùn pẹ̀lú ọ̀pá ìwọ̀n ǹnkan ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ Ó wọn ìhà àríwá ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá ìwọn nǹkan O wọn ìhà gúsù ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá wíwọ̀n nǹkan Lẹ́yìn èyí ni ó wà yí padà sí ìhà ìwọ̀ oòrùn o sì wọ̀n ọ́n ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pa wíwọ̀n Báyìí ní ó wọn agbégbé ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin Ó ní ògiri kan yípo rẹ̀, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀, àti ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, láti ya ibi mímọ́ sọ́tọ̀ kúrò ní ibi tí gbogbo ènìyàn ń lọ sọ́tọ̀ Ògo Padà Sí Inú Ilé Ọlọ́run Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi gba ti ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn, mo sì ri ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì ń bọ láti ìhà ìlà oòrùn Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi, ìtànsán ògo rẹ̀ sì bo ilẹ̀ Ìran tí mo rí dàbí ìran tí mo rí lẹ́bàá odò Kébárì, mo sì dorí kodò Ògo Olúwa gba ọ̀nà tí o dojúkọ ìhà ìlà oòrùn wọ inú ilé Ọlọ́run wá Mo ni ìrusókè ẹ̀mí, ó sì mú mi lọ inú ilé ìdájọ́, sì kíyèsí ògo Olúwa kún inú ilé Ọlọ́run Nígbà tí ọkùnrin náà dúró ní ẹ̀gbẹ́ mi, mo gbọ́ ẹnìkan tí ó bá mi sọ̀rọ̀ láti inú ilé Ọlọ́run Ó sì wí pé Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ibi ìgunwà mi àti ibi tí ó wà fún àtẹ́lẹsẹ̀ mi, Ibi yìí ni èmi yóò máa gbé ní àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí láéláé Ilé Ísírẹ́lì kò ní ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́ láéláé àwọn tàbí àwọn Ọba wọn nípa àgbèrè àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn Ọba wọn ní ibi gíga Nígbà tí wọ́n ba gbé ìlóro ilé wọn kangun sí ìlóro ilé mi àti ìlẹ̀kùn wọn sì ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀kùn mi, pẹ̀lú ògiri nìkan ní àárin èmi pẹ̀lú wọn, wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ìwà ìríra wọn Nígbà náà ni mo pa wọ́n run ní ìbínú mi Nísinsin yìí jẹ́ kí wọn mú ìwà àgbérè wọn àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn Ọba wọn kúrò ni iwájú mi, èmi yóò sì gbé àárin wọn láéláé Ọmọ ènìyàn, ṣàpèjúwe ilé Ọlọ́run náà fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, lè tì wọ́n sì jẹ́ kí wọn wo àwòrán ilé náà, tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀ Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀ Èyí yìí ní òfin ilé Ọlọ́run náà Gbogbo àyíká lórí òkè gíga ní yóò jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ Bí èyí ni òfin tẹ́ḿpìlì náà Ìwọ̀nyí ni wíwọ̀n pẹpẹ ìrúbọ ní gígùn ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni jíjìn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni fífẹ̀, igun rẹ̀ yípo àti etí rẹ̀ jẹ́ ibú àtẹ́lẹwọ́ kan Èyí yìí sì ni gíga pẹpẹ ìrúbọ náà Láti ìsàlẹ̀ rẹ̀ ni ilẹ̀ títí dé ìsàlẹ̀ igun rẹ̀, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga o sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀ Ibi ìdáná pẹpẹ ìrúbọ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga, ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì yọrí jáde sókè láti ibi ìdáná Ibi ìdáná pẹpẹ náà jẹ́ igun mẹ́rin mẹ́rin lọ́gbọgba, ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní gígùn, o sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní fífẹ̀ Igun ni apá òkè náà jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọgba, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní fífẹ̀, pẹ̀lú etí tí ó jẹ́ ìdáji ìgbọ̀nwọ́, ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan yípo Àtẹ̀gùn pẹpẹ ìrúbọ náà dojúkọ ìlà oòrùn Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé, Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ohun tí Olúwa wí Ìwọ̀nyí yóò jẹ́ òfin fún ìrúbọ ẹbọ sísun àti wíwọ́n ẹ̀jẹ̀ sórí pẹpẹ nígbà tí a bá mọ pẹpẹ tán Ẹ̀yin ní láti mú ọ̀dọ́ akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrékọjá fún àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Léfì, tí ìdílé Sádókù tí ó wá sí agbègbè láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún mi ní Olúwa Ọba wí Ẹ ni láti mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí ẹ sì fi sórí ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà lórí pẹpẹ, àti lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ìjòkòó náà àti sí gbogbo etí rẹ̀ yípo, ìwọ yóò sì sọ pẹpẹ di mímọ́, ìwọ yóò sì ṣe ètùtù rẹ̀ Ìwọ gbọdọ̀ mú akọ màlúù fún ìrékọjá, ìwọ yóò sì sun ún ní apá ibi tí a ṣàmì sí ní agbègbè ilé Ọlọ́run ní ìta ibi mímọ́ Ní ọjọ́ kejì ìwọ yóò fi ewúrẹ́, òbúkọ aláìlábàwọ́n fún ẹbọ ẹsẹ, a sì gbọdọ̀ sọ pẹpẹ di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ́ di mímọ́ pẹ̀lú akọ màlúù Nígbà tí ìwọ bá parí ìsọdimímọ́, ìwọ yóò fi ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ọ̀dọ́ àgbò aláìlábàwọ́n láti inú agbo fún ìrúbọ Ìwọ yóò mú wọn lọ sí iwájú Olúwa , àwọn àlùfáà ni yóò fi iyọ̀ wọ́n wọn, wọn yóò sì fi wọ́n rúbọ sísun sí Olúwa Fún ọjọ́ méje, ìwọ ní láti pèsè akọ ewúrẹ́ kan lójoojúmọ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Ìwọ yóò sì pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò láti inú agbo, méjèèjì yóò sì jẹ́ aláìlábàwọ́n Fún ọjọ́ méje wọn yóò jẹ́ ètùtù fún pẹpẹ, wọn yóò sì sọ ọ́ di mímọ́ nípa bẹ́ẹ̀ wọn yóò yà á sọ́tọ̀ Ní ìparí ọjọ́ wọ̀nyí, láti ọjọ́ mẹ́jọ síwájú, àwọn àlùfáà ni yóò gbé àwọn ẹbọ sísun rẹ àti ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ Lẹ́yìn náà, èmi yóò tẹ́wọ́gba yín ní Olúwa Ọba wí Àwọn Ọmọ Ọba, Àwọn Léfì Àti Àwọn Àlùfáà Lẹ́yìn náà ni ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí ibi mímọ́, èyí tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ó sì wà ní títì Olúwa sọ fún mi, Ẹnu ọ̀nà yìí ni kí ó wà ní títì A kò gbọdọ̀ sí i sílẹ̀ kò sí ẹni tí o gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé Ó gbọdọ̀ wà ní títì nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí gbà ibẹ̀ wọlé Ọmọ aládé fúnra rẹ̀ ní o lè jókòó ní ẹnu ọ̀nà náà kí o sì jẹun níwájú Olúwa Ó gbọdọ̀ gba ọ̀nà ìlóro ẹnu ọ̀nà wọlé kí ó sì gba ibẹ̀ jáde Lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà mú mi gba ẹnu ọ̀nà àríwá lọ sí iwájú ilé Ọlọ́run Mo wò ó mo sì rí ògo Olúwa tí ó kún inú ilé Olúwa , mo sì dojúkọ ilẹ Olúwa sì sọ fún mì pé, Ọmọ ènìyàn, wò dáadáa, fetí sílẹ̀ dáadáa kí o sì fiyèsí ohun gbogbo tí mo sọ fún ọ nípa ofin lórí ilé Olúwa náà Fiyèsí ẹnu ọ̀nà ilé Ọlọ́run náà àti gbogbo àbájáde ibi mímọ́ Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé Ísírẹ́lì pé, Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọba wí Ìwà ìríra rẹ tí tó gẹ́ẹ́, ìwọ ilé Ísírẹ́lì! Ní àfikún pẹ̀lú gbogbo àwọn ìwà ìríra rẹ tí ó kù, ìwọ mú àwọn àjòjì aláìkọlà àyà àti ara wá sí inú ibi mímọ́ mi, ní lílo ilé mi ní ìlòkúlò nígbà tí ìwọ fi oúnjẹ fún mi, ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ìwọ sì ba májẹ̀mú mi jẹ́ Dípò kí ìwọ pa òfin mi mọ́, ìwọ fi àwọn mìíràn sí ibi mímọ́ mi Èyí yìí ní Olúwa Ọba wí Àjòjì aláìkọlà àyà àti ara kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi, àti pẹ̀lú àwọn àjòjì tí ń gbé ní àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì  Àwọn Léfì tí wọn rìn jìnnà kúrò lọ́dọ̀ mi nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sìnà, ti wọ́n sì ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi láti tọ àwọn ère wọn lẹ́yìn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀sẹ̀ wọn Wọn le sìn mi ní ibi mímọ́ mi, kí wọn ṣe ìtọ́jú àwọn ẹnu ọ̀nà ilé Ọlọ́run, kí wọn sì ṣe ìránṣẹ́ nínú rẹ̀ wọn le pa ẹbọ sísun, ki wọn sì rúbọ fún àwọn ènìyàn, kí wọn sì dúró níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn níwájú àwọn ère wọn, tí wọn sì mu ilé Ísírẹ́lì subú sínú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí náà, Èmi tí búra nípa nína ọwọ́ sókè pé, wọn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ní Olúwa Ọba sọ Wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi láti se ìránṣẹ́ fún mi, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí súnmọ́ ìkankan nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ẹbọ mi mímọ́ jùlọ wọn gbọdọ̀ gba ìtìjú ìwà ìríra wọn Síbẹ̀ èmi yóò mu wọn sí ìtọ́jú ilé Ọlọ́run àti gbogbo isẹ́ tí a gbọdọ̀ se níbẹ̀  Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Léfì àti àwọn ìran Sádómù tí fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn gbọdọ̀ súnmọ́ iwájú láti ṣe ìránṣẹ́ ní iwájú mi, láti rú ẹbọ ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ni Olúwa Ọba sọ Àwọn nìkan ni ó gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi àwọn nìkan ní o gbọdọ̀ sùnmọ́ tábìlì mi láti ṣe ìránṣẹ́ ni iwájú mi, ki wọn sì ṣe iṣẹ́ ìsìn mi  Nígbà ti wọ́n wọ àwọn ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú, wọn yóò wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, wọn kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní àwọn ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú tàbí ni inú ilé Ọlọ́run Wọ́n ní láti dé fìlà ọ̀gbọ̀ sí orí wọn àti àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀gbọ̀ sí ìdí wọn Wọn kò gbọdọ̀ wọ ohunkóhun tí yóò mú wọn làágùn Nígbà tí wọ́n bá lọ sì àgbàlá òde níbi tí àwọn ènìyàn wà, wọn gbọdọ̀ bọ́ aṣọ tí wọ́n fi ń siṣẹ́ ìránṣẹ́, ki wọn sì fi wọn sílẹ̀ sí àwọn yàrá mímọ́ náà, kí wọn kí ó sì wọ aṣọ mìíràn, kí wọn kí ó má ba à sọ àwọn ènìyàn di mímọ́ nípasẹ̀ aṣọ wọn  Wọn kò gbọdọ̀ fá irun, wọn kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí irun wọn gùn, ṣùgbọ́n wọn gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí wọn wà ní gígẹ̀ Àlùfáà kankan kò gbọdọ̀ mu ọtí nígbà tí ó bá wọ àgbàlá tí inú Wọn ko gbọdọ̀ fẹ́ opó ni ìyàwó, wọn kò sì gbọdọ̀ kọ ìyàwó wọn sílẹ̀ Wọ́n lè fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ti kò tí i mọ ọkùnrin rí, tí ó sì jẹ́ ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tàbí kí wọn fẹ́ àwọn opó Àlùfáà Wọn ní láti fi ìyàtọ̀ tí ó wà nínú mímọ́ àti aláìmọ́ kọ́ àwọn ènìyàn mi, kí wọn sì fi bi wọn yóò ṣe dá aláìmọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí mímọ́ hàn wọ́n  Nínú èyíkéyi èdè-àìyedè, àwọn Àlùfáà ní ó gbọdọ̀ dúró gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin mi Wọ́n ní láti pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́ fún gbogbo àṣẹ, wọn sì gbọdọ̀ lo ọjọ ìsinmi mi ní mímọ́  Àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa sísún mọ́ òkú ènìyàn ṣùgbọ́n ti òkú ènìyàn yẹn bá jẹ́ bàbá tàbí ìyá rẹ̀, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin ti kò i ti lọ́kọ, nígbà náà o le sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ Lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, ki òun kí ó dúró fún ọjọ́ méje Ní ọjọ́ ti yóò wọ àgbàlá ti inú ni ibi mímọ́ láti se ìránṣẹ́ ibi mímọ́, ni kí òun kí o rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Olúwa Ọba wí  Èmi ni kì ó jẹ́ ogún tí àwọn Àlùfáà yóò ní Ẹ kò gbọdọ̀ fún wọn ni ìpín kankan ní Ísírẹ́lì Èmi ni yóò jẹ́ ìpín wọn Wọn yóò jẹ ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ni Ísírẹ́lì ni yóò jẹ́ ti wọn Èyí tí ó dára jùlọ nínú gbogbo àkọ́so èso àti ti ẹ̀bùn pàtàkì yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà Ẹ ní láti fún wọn ní ìpín àkọ́kọ́ nínú èso ilẹ̀ yìí kí ìbùkún lè wà lórí gbogbo ilé yìí Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ jẹ́ ohunkóhun bí i ẹyẹ tàbí ẹrankọ, tí ó ti kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí ti ẹranko ńlá fà ya Ilẹ̀ Pínpín  Nígbà ti ẹ̀yin bá pín ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, ẹ gbọdọ̀ gbé ìpín ilẹ̀ kan kalẹ̀ fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí agbègbè mímọ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ogún ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ gbogbo agbègbè náà ni yóò jẹ́ mímọ́ Lára èyí, apákan ti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí o jẹ́ ẹ̀ẹ́dégbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ ní ó gbọdọ̀ wà fún ibi ìyàsímúmọ́ fún Ọlọ́run, pẹ̀lú ibẹ̀ tí ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ fún ilẹ̀ tí ó yí ibi mímọ́ náà ká Ilẹ̀ tí ó yí i ká yìí yóò wà bẹ́ẹ̀ láì lò ó Ní agbègbè ibi mímọ́, wọn ya ibi kan sọ́tọ̀ kí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní fífẹ̀ Ní inú rẹ ni ilẹ̀ ti a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa yóò wà, ìyẹn ibi mímọ́ jùlọ Yóò jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà fún àwọn àlùfáà, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ àti àwọn tí ó súnmọ́ àlùfáà ní iwájú Olúwa Ibẹ̀ yóò jẹ ibi tí yóò wà fún ilé gbígbé wọn, bákan náà ni yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún ilé Olúwa Agbègbè kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní fífẹ̀ yóò jẹ́ ti àwọn ará Léfì, tí ó ń ṣiṣẹ ìránṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì, gẹ́gẹ́ bi ìní wọn fún ìlú wọn láti máa gbé ibẹ̀  Ìwọ yóò fi ìlú náà ti agbègbè rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, papọ̀ mọ́ ibi mímọ́ fún àwọn ilé Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìní yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Ísírẹ́lì  Àwọn ọmọ aládé ni yóò bá ibi mímọ́ pààlà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan agbégbé tí ó jẹ ibi mímọ́ àti ohun tí ó jẹ́ ti ìlú Yóò fẹ̀ sẹ́yìn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn láti apá ìwọ̀ oòrùn àti si ìlà oòrùn, láti apá ìlà oòrùn, gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ láti ìwọ̀ oòrùn sí ààlà ìlà oòrùn, ti ìṣe déédéé rẹ̀ yóò jẹ́ ti ọ̀kan lára àwọn ìpín ẹ̀yà Ilẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ìpín rẹ̀ ní Ísírẹ́lì Àwọn ọmọ aládé mìíràn kò ní rẹ́ àwọn ènìyàn mi jẹ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ kí àwọn ilé Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà wọn  Èyí yìí ni Olúwa Ọba wí Ìwọ ti rìn jìnnà tó, Ẹ̀yin ọmọ aládé tí Ísírẹ́lì! Fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ rẹ sílẹ̀ kí ó sì se èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ Dáwọ́ gbígbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọba sọ Ìwọ gbọdọ̀ lo òṣùnwọ̀n tó tọ́ àti efà títọ́ àti bátì títọ́ Éfà àti batì gbọdọ̀ jẹ́ bákan náà, kí bátì tí ó gba ìdàmẹ́wàá hómérì, àti ẹfa ìdámẹ́wàá hómérì Hómérì ni kí ó jẹ́ òṣùnwọ̀n tí wọn yóò lò fún méjèèjì Ṣékélì ní kí o gba ogún gérà Ogún ṣekeli pẹ̀lú ṣékélì márùndínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú ṣékélì mẹ́ẹ̀dógún yóò jẹ́ mínà kan  Èyí yìí ni ẹ̀bùn pàtàkì tí o gbọdọ̀ ṣe éfà kẹ́fà láti inú hómérì ọkà kọ̀ọ̀kan àti éfà kẹ́fà láti inú hómérì báálì kọ̀ọ̀kan Ìpín òróró tí a júwe, tí a fi bátì wọ̀n, ni ìdámẹ̀wàá bátì láti inú kórì Bákan náà ni àwa yóò mú àgùntàn kan láti inú agbo ẹran tí ó jẹ́ igba láti inú kanga omi pápá oko tútù tí Ísírẹ́lì Ìwọ̀nyí ni wọn yóò lò fún àwọn ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ẹbọ sísun àti ìdàpọ̀ ọrẹ ẹbọ láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àwọn ènìyàn, ní Olúwa Ọba sọ Gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà ni yóò kópa nínú ẹ̀bùn pàtàkì fún ìlò àwọn ọmọ aládé ni Ísírẹ́lì Yóò jẹ́ ojúṣe ọmọ aládé láti pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ ẹbọ mímu níbi àṣè gbogbo, ti oṣù tuntun àti ní àwọn ọjọ ìsìnmi ni gbogbo àjọ ilé Ísírẹ́lì Oun yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù fún ilé Ísírẹ́lì  Èyí yìí ní Olúwa Ọba wí Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ìwọ yóò mú akọ màlúù aláìlábàwọ́n kì o sì sọ ilé Ọlọ́run di mímọ́ Àlùfáà ni yóò mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o sì fi si ẹnu ilẹkùn ilé Ọlọ́run, àti sí ara àwọn ilẹ̀kùn tí ó wà ní àgbàlá ti inú Ìwọ yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ọjọ́ kéje oṣù fún àwọn tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀ọ́mọ̀dá tàbí nínú àìmọ̀kan nítorí náà, ìwọ yóò ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ilé Ọlọ́run  Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ní ìwọ yóò ṣe àjọ ìrékọjá, àṣè ọjọ́ méje, àsìkò yìí ní ẹ̀yin yóò jẹ àkàrà tí kò ni ìwúkàrà Ní ọjọ́ náà ní ọmọ aládé yóò pèsè akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀sẹ̀ fún ara rẹ̀ àti fún gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà Ní ojoojúmọ́ ni àárin ọjọ́ méje àṣè ni òun yóò pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje tí kò ní àbùkù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa , àti akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Òun yóò sì pèsè éfà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ jíjẹ Éfà kan fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti éfà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú hini òróró kan fún éfà kan  Láàárin ọjọ́ méje àṣè náà, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù kéje, òun yóò tún pèsè nǹkan bí ti tẹ́lẹ̀, fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú òróró  Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọba wí Ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn ni kí a tì pa fún ọjọ́ mẹ́fà tí a fi ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìsinmí àti ní ọjọ́ oṣù tuntun ni kí a sí i Ọmọ aládé ni kí ó wọlé láti ìta tí ó kangun sí àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà, kí ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àwọn àlùfáà ni yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ ìdàpọ̀ Òun ni yóò jọ́sìn ní ìloro ilé ní ẹnu ọ̀nà, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde, ṣùgbọ́n wọn kò ni ti ilẹ̀kùn títí ìrọ̀lẹ́ Ní àwọn ọjọ́ ìsinmi àti àwọn oṣù tuntun ni kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ́sìn ní iwájú Olúwa ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmí ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ éfà kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú éfà kọ̀ọ̀kan Àti ni ọjọ́ oṣù tuntun, ẹgbọrọ màlúù kan àìlábàwọ́n, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́fà, àti àgbò kan wọn o wà láìlábàwọ́n Yóò si pèsè ọrẹ-ẹbọ jíjẹ éfà fun ẹgbọrọ akọ màlúù, àti éfà kan fun àgbò kan, àti fun àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bi èyí ti ipá rẹ̀ ká, àti hínì òróró kan fún éfà kan Nígbà tí ọmọ aládé bá wọlé, ó gbọdọ̀ gbá àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà wọ inú, kí ó sì gba ibẹ̀ jáde  Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá ṣíwájú Olúwa ni àwọn àjọ tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu ọ̀nà ìhà gúsù jáde ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gba tí ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá jáde Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé padà, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde Ọmọ aládé gbọdọ̀ wà ní àárin wọn, kí ó wọlé nígbà tí wọn bá wọlé, kí ó sì jáde nígbà tí wọn bá jáde  Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ éfà kan pẹ̀lú àgbò kan, àti pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá se wu onílúlùkù, Pẹ̀lú hini òróró kan fún éfà kan Nígbà tí ọmọ aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn ni kí ó wà ni sísí sílẹ̀ fún-un Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi Lẹ́yìn náà, oun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu ọ̀nà  Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀ Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú éfà àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí Nítorí náà ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo  Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọba sọ Tí ọmọ aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tíwọn nípa ogún jíjẹ Tí ó bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọkan lára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ọmọ le pa mọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀ Lẹ́yìn náà yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọmọ aládé Ogún ìní rẹ̀ jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan Ó jẹ́ tiwọn Ọmọ aládé kò gbọdọ̀ mú ìkankan lára ogún ìní àwọn ènìyàn, tàbí mú wọn kúrò níbi ohun ìní wọn Ó ní láti fi ogún ìní rẹ̀ láti inú ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí a ma baà ya ìkankan kúrò lára ìní rẹ̀  Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi kọjá ní àbáwọlé tí ó wà lẹ́bá ẹnu ọ̀nà, sí àwọn yàrá mímọ́ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, èyí tí ó jẹ́ tí àwọn àlùfáà, ó sì fi ibi kan hàn mí ní apá ìwọ̀ oòrùn O sọ fún mi pé, Èyí yìí ni ibi tí àwọn àlùfáà yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ ìdálẹ́bi àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti tí wọn yóò ṣe ọrẹ ẹbọ jíjẹ, láti má se jẹ́ kí wọn mú wọn wá sí ìta àgbàlá kí wọn sì ya àwọn ènìyàn sí mímọ́ Ó sì mú mi lọ sí ìta àgbàlá, ó sì mú mi yí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ká, mo sì ri àgbàlá mìíràn ní igun kọ̀ọ̀kan Ní ìgun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìta àgbàlá tí ó pẹnupọ̀, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àgbàlá kọ̀ọ̀kan ni igun kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n kan náà Ní agbègbè inú ikọ̀ọ̀kan nínú àgbàlá náà ni ọwọ́ ilẹ̀ kan wà yíká wọn, a sì ṣe ibi ìdáná si abẹ́ ọwọ́ náà yípo Ó sì wí fún mi pé, Ìwọ̀nyí ni àwọn ilé ìdáná níbi tí o ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì yóò ti ṣe ẹbọ fún àwọn ènìyàn Odò Láti Inú Tẹ́ḿpìlì Náà Ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí àbáwọlé tẹ́ḿpìlì náà, mo sì rí omi tí ó ń tú jáde láti abẹ́ ìloro tẹ́ḿpìlì náà sí apá ìhà ìlà oòrùn Omi náà ń tú jáde sí ìsàlẹ̀ láti abẹ́, ní ìhà gúsù tẹ́ḿpìlì náà, ní ìhà gúsù pẹpẹ Ó wá mú mi gba ojú ọ̀nà àríwá jáde, ó sì mú mi yí ìta ojú ọ̀nà ìta tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn, omi náà sì ń ṣàn láti ìhà gúsù wá Bí ọkùnrin náà ti lọ sí apá ìhà ìlà oòrùn pẹ̀lú okùn wíwọ̀n nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, o wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi gba ibi odò kan tí kòì jìnjù kókósẹ̀ lọ Ó sì wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba ibi odò tí o jìn ní ìwọ̀n orúnkún Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba odò tí ó dé ìbàdí Ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ṣùgbọ́n nísinsìnyí odò tí ń kò lè kọjá rẹ̀ ni, Nítorí pé odò tí ó kún, ó sì jìn tó èyí tí wọ́n le lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ odò tí ẹnikẹ́ni kò le dá kọjá ni Ó bi mí léèrè, pé Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ o rí èyí Lẹ́yìn náà ó mú mi padà sí etí odò Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì odò Ó sọ fún mi pé, Odò yìí ń ṣàn sí ìhà ìlà oòrùn, ó sì lọ sí ìsàlẹ̀ títí dé Árábù, níbi tí ó ti wọ inú òkun, omi tí o wà níbẹ̀ jẹ́ èyí tí ó tutù Àwọn ohun alààyè tí o ń rákò yóò máa gbé ní íbikíbi tí odò ti ń ṣàn Ẹja yóò pọ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀, nítorí pé odò ń ṣàn síbẹ̀ ó sì mú kí omi iyọ̀ tutù nini nítorí náà níbi tí omi ti ń ṣàn gbogbo nǹkan ni yóò wà ni ààyè Àwọn apẹja yóò dúró ní etí bèbè odò láti Éńgédì títí dé Énégíláémù àyè yóò wa láti tẹ́ àwọ̀n wọn sílẹ̀ Orísìírísìí ẹja ni yóò wà gẹ́gẹ́ bí ẹja omi òkun ńlá Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀ Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò dàgbà ní bèbè odò méjèèjì Ewé wọn kì yóò sì gbẹ, tàbí ní èso nítorí pé odò láti ibi mímọ́ ń ṣàn sí wọn Èso wọn yóò dàbí oúnjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Ọba wí Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárin àwọn ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì, pẹ̀lú ìpín méjì fún Jóṣéfù Ìwọ yóò pín ilẹ̀ náà déédéé ní àárin wọn Nítorí pé mo búra nípa nína ọwọ́ sókè láti fi fún àwọn baba ńlá yin, ilẹ̀ yìí yóò di ogún ìní yín Èyí yìí ni yóò jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà Ní ìhà àríwá yóò lọ láti omi òkun ńlá ní ibi ọ̀nà Hétílónì gbà tí Hámátì sí Sídádì, Bérótalì àti Síbíráímù títí dé Hásà Hátíkọ, èyí tí ó wà ní ààlà Háúránù Ààlà yóò fẹ̀ láti òkun lọ sí Hásà Énánù, ní apá ààlà ti Dámáskù, pẹ̀lú ààlà tí Hámátì lọ sí apá àríwá Èyí ni yóò jẹ́ ààlà ní apá ìhà àríwá Ní ìhà ìlà oòrùn ààlà yóò wá sí àárin Háúránù àti Dámásíkù, lọ sí apá Jọ́dánì láàárin Gílíádì àti ilẹ̀ oòrùn àti títí dé Támárì Èyí ní yóò jẹ́ ààlà ìlà oòrùn Ní ìhà gúsù yóò lọ láti Támérì títí dé ibi omi méríba Kádési, lẹ́yìn náà ni ìhà wádìí tí Éjíbítì lọ sí òkun ńlá Èyí ni yóò jẹ́ ààlà gúsù Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, òkun ńlá ni yóò jẹ́ ààlà títí dé ibi kan ni òdìkejì lẹ́bàá Hámátì Èyí yìí ni yóò jẹ ààlà ìhà ìwọ̀ oòrùn Ìwọ ní láti pin ilẹ̀ yìí ní àárin ara yín gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì Ìwọ yóò pín gẹ́gẹ́ bí ìní fún ara yín àti fún àwọn àjòjì tí ó ń gbé ní àárin yín tí ó sì ní àwọn ọmọ Ìwọ yóò sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ àwọn ará Ísírẹ́lì papọ̀ mọ́ yin ni kí a pín ìní fún wọn ní àárin àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì Ní àárin ẹ̀yàkẹyà tí àwọn àlejò ń gbé wọn gbọdọ̀ fi ìní tirẹ̀ fún-ún, ní Olúwa Ọba pa lásẹ Pín Pín Ilẹ Náà Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn Ní òpin àríwá, Dánì yóò ni ìpín kan èyí yóò tẹ̀lé ọ̀nà Hétílónù sí létí Hámátì Hásárì Énánù àti ààlà àríwá tí Dámásíkù tí ó kángun sí Hámátì yóò jẹ́ ara ààlà rẹ̀ láti ìhà ìlà oòrùn títí lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn Àsárì yóò ní ìpín kan yóò jẹ́ ààlà agbégbé dánì láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ oòrùn Náfítalì yóò ní ìpín kan èyí yóò jẹ́ ààlà agbégbé Ásárì láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn Mánásè yóò ní ìpín èyí yóò jẹ́ ààlà ti agbégbé Náfátalì láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn Éfúráímù yóò ní ìpín kan èyí yóò jẹ́ ààlà agbégbé Mánásè láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ oòrùn Rúbẹ́nì yóò ní ìpín kan èyí yóò jẹ́ ààlà agbégbé Éfúráímù láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn Júdà yóò ní ìpín kan èyí yóò jẹ́ ààlà agbégbé Rúbẹ́nì láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn Ààlà agbégbé Júdà láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn yóò jẹ́ ìpín tí ìwọ yóò gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì Yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀, gígùn rẹ̀ láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn yóò jẹ́ bákan náà pẹ̀lú àwọn ìpín ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ilé mímọ́ yóò wà ní àárin gbùngbùn rẹ̀ Ìpín pàtàkì tí ìwọ yóò fifún Olúwa yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ Èyí yóò jẹ́ ìpín ibi mímọ́ fún àwọn àlùfáà Yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn ní ìhà àríwá, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà oòrùn, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn ní ìhà gúsù Ní àárin gbùngbùn rẹ̀ ní ilé fún Olúwa yóò wà Èyí yóò wà fún àwọn àlùfáà tí a yà sí mímọ́, àwọn Sódókítì tí wọn jẹ́ olóòótọ́ nínú sí sin mí, ti wọn kò sì sáko lọ bí ti àwọn Léfì ṣe se nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì sáko lọ Èyí yóò jẹ́ ẹ̀bùn pàtàkì fún wọn láti ara ìpín ibi mímọ́ ilẹ̀ náà, ìpín tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, tí ó jẹ́ ààlà agbégbé àwọn Léfì Lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbégbé àwọn àlùfáà, àwọn Léfì yóò pín ìpín kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ Gígùn rẹ̀ ní àpapọ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹẹdọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́, àti fífẹ̀ rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìgbọ̀nwọ́ Wọn kò gbọdọ̀ tà tàbí jìrọ̀ ìkankan nínú rẹ̀ Èyí yìí ni ó dára jùlọ lára ilẹ náà, a kò sì gbọdọ̀ fifún ẹlòmíràn nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa Agbègbẹ tí o ṣẹ́kù, tí ń ṣe ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, yóò wà fun àjùmọ̀lò àwọn ará ìlú ńlá náà fún ilé gbígbé àti fún ilẹ̀ ìjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sàn Ìlú ńlá náà yóò wà ní àárin rẹ̀, Ìwọ̀nyí sì ní bi a ṣe wọ̀n ọ́n ní ìhà àríwá ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́, ni ìhà gúsù ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́, ní ìhà ìlà oòrùn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ àti ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ Ilẹ̀ ìjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn fún ìlú ńlá náà yóò jẹ igba àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà gúsù, ìgbà àti ìgbà pẹ̀lú àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Èyí tí ó kù ní agbégbé náà, tí ó jẹ́ ààlà ìpín ibi mímọ́, gígùn rẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìlà oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Ìpèsè rẹ̀ yóò fi kún oúnjẹ fún àwọn òsísẹ́ ìlú ńlá náà Àwọn òsìsẹ́ láti ìlú ńlá náà, tí ó ń dáko níbẹ̀ yóò wá láti gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì Gbogbo ìpín náà yóò rí bákan náà ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, èyí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní ẹgbẹ kọ̀ọ̀kan Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì ìwọ yóò fi ìpín ibi mímọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kan, papọ̀ mọ́ ohun ìní ìlú ńlá náà Èyí tí ó sẹ́kù ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì agbégbé tí ó jẹ́ ìpín ibi mímọ́ àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ aládé Yóò lọ títí dé ìhà ìlà oòrùn láti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ti ìpín ibi mímọ́ títí dé ààlà ìlà oòrùn Agbégbé méjèèjì wọ̀nyí ni gígùn àwọn ìpín ẹlẹ́yàmẹ́yà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ aládé, àti ìpín ibi mímọ́ pẹ̀lú tẹ́ḿpìlì yóò wa ní àárin wọn Ilẹ̀ ìní àwọn Léfì àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò wà ni àárin agbégbé tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ aládé Agbégbé tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ aládé yóò wà ní àárin ààlà tí Júdà àti ààlà tí Bénjámínì Níti àwọn ẹ̀yà tí ó kù Bẹ́ńjámínì yóò ní ìpín kan Yóò wà láti ìhà ìlà oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀ oòrùn Símónì yóò ní ìpín kan Yóò jẹ́ ààlà agbégbé Bẹ́ńjámínì láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn Ísàkárì yóò ní ìpín kan yóò jẹ́ ààlà agbégbé Símónì láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn Sébúlónì yóò ní ìpín kan yóò jẹ́ ààlà agbégbé Isàkárì láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn Gádì yóò ní ìpín yóò jẹ́ ààlà agbégbé Sébúlónì láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn Ààlà tí gúsù Gádì yóò dé gúsù láti Támárì lọ sí odò Méríbà Kádésì lẹ́yìn náà títí dé Wádì ti Éjíbítì lọ sí òkun ńlá fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ìwọ̀nyí ní yóò sì jẹ́ ìpín wọn ní Olúwa Ọba wí Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ̀yin o fi ìbò pín ní ogún fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, wọ̀nyí sì ni ìpín wọn, ní Olúwa Ọlọ́run wí Ìwọ̀nyí ní yóò jẹ́ ẹnu ọ̀nà àbájáde ìlú ńlá náà Bẹ̀rẹ̀ láti ìhà àríwá, ti ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ẹnu ọ̀nà ìlú ńlá náà ní àwa yóò fi orúkọ àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì pè Àwọn ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ìhà àríwá ní yóò jẹ́ ọ̀nà tí Rúbẹ́nì, ọ̀nà tí Júdà ọ̀nà tí Léfì Ní ìhà ìlà oòrùn, èyí tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ni ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà ọ̀nà Jósẹ́fù, ọ̀nà tí Bẹ́ńjámínì àti ọ̀nà tí Dánì Ní ìhà gúsù, èyí tí wíwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ ní ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà ojú ọ̀nà Símónì, ojú ọ̀nà Ísákárì àti ojú ọ̀nà Sébúlónì Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, èyí tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ní ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà ojú ọ̀nà Gádì, ojú ọ̀nà Ásárì àti ojú ọ̀nà Náfítalì Jíjnìnà rẹ̀ yípo yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún ìgbọ̀nwọ́ Orúkọ ìlú náà láti ìgbà náà yóò jẹ́ Olúwa wà níbẹ̀ Idà Ń Bọ̀ Sórí Jérúsálẹ́mù Báyìí, ọmọ ènìyàn, mú ìdá tí ó mú kí o sì fi se abẹ ìfárí onígbàjámọ̀, kí o fi fá irun orí àti irùngbọ̀n rẹ Fi irun yìí sórí ìwọ̀n kí o sì pín in Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ìrun yìí níná láàrin ìlú Mú ìdá kan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú Kí o sì tú ìdá kan yóòkù ká sínú afẹ́fẹ́ Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Ísírẹ́lì Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Èyí ní Jérúsálẹ́mù, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ̀ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀ èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, kò sì pa ìlànà mi mọ́ Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Nítorí pé o ti ṣe àìgbọ́ràn ju àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká lọ, tí o kò sì tẹ̀lé ìlànà mi tàbí kí o pa òfin mi mọ́ O kò tilẹ̀ tún ṣe dáadáa tó àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí Èmi gan an lòdì sí ọ, Jérúsálẹ́mù, n ó sì jẹ ọ́ níyà lójú àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká Nítorí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ, n ó ṣe ohun tí n kò tí ì ṣe rí láàrin rẹ àti èyí tí n kò ní í ṣe irú rẹ̀ mọ́ Nítorí náà láàrin rẹ àwọn baba yóò má a jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ náà yóò máa jẹ baba wọn N ó jẹ ọ́ níyà, n ó sì tú àwọn tó bá ṣẹ́kù ká sínú èfúùfù Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run wí pé, bí mo ṣe wà láàyè, nítorí pé o ti sọ ibi mímọ́ mi di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn àwòrán ẹ̀gbin àti àwọn ohun ìríra rẹ, n ó mú ojú rere mi kúrò lára rẹ n kò ní í da ọ sí tàbí wò ọ́ pẹ̀lú àánú mọ́ Ìdá mẹ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ yóò kú nípa àjàkálẹ̀-àrùn tàbí kí ìyàn run wọ́n ìdá mẹ́ta yóò ṣubú nípa idà lẹ́yìn odi rẹ n ó sì tú ìdá mẹ́ta yóòkù ká sínú èfúùfù, a ó sì máa fi idà lé wọn Ìbínú mi yóò sì dúró, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú gbígbónná mi yóò sì rolẹ̀, n ó sì ti gba ẹ̀san mi Nígbà tí mo bá sì parí ìbínú mi lórí wọn, wọn ó mọ̀ pé Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀ nínú ìtara mi Èmi yóò fi ọ́ ṣòfò, ó sì sọ ọ́ di ẹ̀gàn fún àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká, àti lójú àwọn tó ń kọjá O ó wá di ẹ̀gàn, ẹ̀sín àti ikílọ àti ohun ẹ̀rù àti ìyanu fún àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká nígbà tí mo bá fìyà jẹ ọ́ nínú ìbínú àti nínú ìbínú gbígbóná mi Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀ Nígbà tí mo bá ta ọfà ikú àti ìparun pẹ̀lú ìyàn, n ó ta á láti run ọ́ ni N ó gé ìpèsè oúnjẹ kúrò, n ó sì mú ìyàn wá lọ́pọ̀lọpọ̀ Èmi yóò rán ìyàn àti ẹranko búburú sí i yín, wọn yóò fi yín sílẹ ni àìlọ́mọ Àjàkálẹ̀ àrùn àti ìtàjẹ̀-sílẹ̀ yóò kọjá láàrin yín Èmi yóò si mú idà wá sórí rẹ Èmi Olúwa ló sọ bẹ́ẹ̀ Ìsọtẹ́lẹ̀ Sí Àwọn Òkè Ísírẹ́lì Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé Ọmọ ènìyàn, dojú kọ àwọn òkè Ísírẹ́lì kí o sì sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí wọn wí pé Ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí sí ẹ̀yin òkè ńlá àti àwọn òkè kékèké sí àwọn odò ṣíṣàn àti sí àfonífojì, n ó mú idà wa sórí yín, n ó sì pa ibi gíga yín run N ó wó pẹpẹ yín lulẹ̀, n ó sì fọ́ pẹpẹ tùràrí yín túútúú èmi ó sì pa àwọn ènìyàn yín síwájú àwọn òrìṣà wọn N ó tẹ́ òkú àwọn ará Ísírẹ́lì síwájú òrìsà wọn n ó sì fọ́n egungun wọn yí pẹpẹ wọn ká Gbogbo ibi tí ẹ ń gbé àti àwọn ibi gíga yín ni yóò di píparun, gbogbo pẹpẹ yín ni yóò di ahoro, àwọn òrìṣà yín yóò di fífọ́ túútúú, àwọn pẹpẹ tùràrí yín ni a ó gé lulẹ̀, gbogbo iṣẹ́ yín yóò parẹ́ Àwọn ènìyàn yín yóò ṣubú láàrin yín, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa  Ṣùgbọ́n n ó dá àwọn kan sí nítorí pé díẹ̀ nínú yín ni yóò bọ́ lọ́wọ́ idà, nígbà tí a bá fọ́n yín ká sí gbogbo ilẹ̀ àti orílẹ̀ èdè Àwọn ti ó bọ́ nínú yin yóò sì ránti mi láàrin àwọn orílẹ́-èdè níbi tí wọn o dì wọ́n ní ìgbèkùn lọ, nítorí ti mo ti tọ́ ọkàn àgbèrè wọn ti o ti lọ kúrò, lọ́dọ̀ mi àti pẹ̀lú ojú wọn, ti n sàgbérè lọ sọ́dọ̀ òrìsà wọn, wọn o si sú ara wọn nítorí ìwà ibi ti wọn ti hù nínú gbogbo ìríra wọn Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa àti pé kì í ṣe lásán ni mo ń lérí pé n ó mú ìdààmú bá wọn  Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí Pàtẹ́wọ́ kí o tún fẹsẹ̀ janlẹ̀, kí o wá kígbe síta pé, Ó ṣe! ilé Ísírẹ́lì yóò ṣubú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn nítorí gbogbo ìwà ìríra búburú tí wọ́n hù Wọn yóò ṣubú nípa idà àti ìyàn Ẹni tó wà lókèèrè yóò kú pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn, àti ẹni tó wà nítòsí yóò ṣubú pẹ̀lú idà, ìyàn ni yóò pa ẹni tó bá ṣẹ́kù sílẹ̀ Báyìí ni n ó ṣe mú ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa , nígbà tí òkú àwọn ènìyàn wọn bá wà níbẹ̀ láàrin òrìṣà wọn yí pẹpẹ wọn ká, lórí àwọn òkè gíga gbogbo, àti lórí góńgó òkè àti lábẹ́ igi tútù àti lábẹ́ igi óákù-níbi tí wọ́n ti ń fi tùràrí dídùn rúbọ̀ sí gbogbo òrìṣà wọn Èmi yóò na ọwọ́ mi jáde sí wọn láti mú kí ilẹ̀ náà ṣòfò kí ó sì dahoro dé aṣálẹ̀ ìhà Díbílà-ní gbogbo ibùgbé wọn Nígbà náà ni wọn ó mọ̀ pé Èmi ni Olúwa   Òpin Ti Dé Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Ọmọ, ènìyàn báyìí ni Olúwa Ọlorún wí sí ilé Ísírélì Òpin! Òpin ti dé sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà Òpin tí dé sí ọ báyìí n ó sì tú ìbínú mi jáde sí ọ, n ó dájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ, ń ó sì san-an fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìwà ìríra rẹ Ojú mi kò ní i dá ọ sì bẹ́ẹ̀ ni ń kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú ṣùgbọ́n ń ó san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrin rẹ Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé èmi ni Olúwa Èyí ni Olúwa Ọlọ́run wí Àjálù, àjálù lórí àjálù ń bọ̀ Òpin ti dé! Òpin ti dé, ó ti dìde lòdì sí ọ Ó ti dé! Ìparun ti dé sórí yín gbogbo, ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ náà Àsìkò ti tó, ọjọ́ wàhálà ti súnmọ́ etílé kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí òkè Mo ṣetán láti tú ìbìnú gbígbóná mi lé ọ lórí àti láti lo ìbínú mi lórí rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ, n ó sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bi gbogbo ìwà ìríra rẹ Ojú mi kò ní i dá ọ sí, ń kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú ń o san-an fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà ìwà àti gbogbo ìwà ìríra tí wà láàrin rẹ Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé èmi Olúwa lo kọlù yín Ọjọ́ náà ti dé! O ti dé Ìparun ti bú jáde, ọ̀pá ti tan ná, ìgbéraga ti sọ jáde! Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kú, tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, kò sí ọrọ̀ ko si ohun ti o niye Àsìkò náà ti tó ọjọ́ náà tidé, kí ẹni tó n rajà má se yọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ki ontàjà má ṣe ṣọ̀fọ̀ torí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn Nítorí pé ontàjà kò ni ri ilé tó tà gbà níwọ̀n ìgbà ti awọ̀n méjèèjì bá wà láyé torí ìran tó kan ènìyàn yìí kò ní yí padà Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò gba ara rẹ̀ là Bí wọn tilẹ̀ fọn fèrè ogun tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀, kò sẹ́ni tí yóò lọ ojú ogun, torí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn Idà wà níta, àjàkálẹ̀-àrùn àti ìyàn wà nílé, idà yóò pa ẹní tó bá wà ní orílẹ èdè, àjàkálẹ̀-àrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà, wọn yóò sì wà lórí òkè bí i àdàbà inú àfonífojì, gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀, olúkúlùkù nítorí àìṣedédé rẹ̀ Gbogbo ọwọ́ yóò rọ, gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi Wọn o wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ẹ̀rù yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, ìtìjú yóò mù wọn, wọn ó sì fá irun wọn Wọn ó dà fàdákà wọn sí ojú pópó, wúrà wọn ó sì dàbí èérí ìdọ̀tí fàdákà àti wúrà wọn kò ní le gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná Olúwa Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn Wọn n ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀sọ́ wọn, tí ó lẹ́wà, wọn sì ti fi ṣe òrìṣà, wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀ Nítorí náà, ní o sọ àwọn ǹnkan wọ̀nyí di ohun èérí tabi ìdọ̀tí fún wọn Èmi yóò sì fi àwọn ǹnkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àlejò àti fún àwọn ènìyàn búburú ayé, wọn ó sì sọ ọ di aláìmọ́ Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn, wọn ó sì sọ ibi iṣúra mi di aláìmọ́ àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀ wọn ó sì bà á jẹ́ Rọ ẹ̀wọ̀n irin, torí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀, ìlú náà sí kún fún ìwà ipá Èmi yóò mú kí orílẹ̀ èdè ti búburú rẹ pọ̀ jù gba ilé wọn ń ó sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́ Nígbà tí ìpayà bá dé, wọn ó wá àlàáfíà, ṣùgbọ́n kò ní sí Wàhálà lórí wàhálà yóò dé, ìdágìrì sókè lórí ìdágìrì, Nígbà náà ni wọn ó wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn alàgbà Ọba yóò sọ̀fọ̀, ọmọ aláde yóò wà láì ní ìrètí ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn, nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa Ìbọ̀rìṣà Nínú Ile Ní ọjọ́ karùn-ún , oṣù kẹfà ọdún kẹfà bí mo ṣe jókòó nílé mi pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Júdà níwájú mi, ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run bà lé mi níbẹ̀ Nígbà tí mo wò, mo rí ohun kan tí o jọ ènìyàn Láti ibi ìbàdí rẹ lọ sísàlẹ̀ dàbí iná, láti ibi ìbàdí yìí sókè sì mọ́lẹ̀ bí idẹ tó ń kọ mọ̀nà Ó na ohun tó dàbí ọwọ́ jáde, ó fi gba mi nírun orí mú, Ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede-méjì ayé àti ọ̀run, ó sì mú mi lọ rí ìran Ọlọ́run, mo sì lọ sí Jérúsálẹ́mù, sí ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà òde àríwá níbi tí ère tí ó ń mú ni bínú wá níwájú mi, Sì kíyèsíi, ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìran ti mo rí ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ó sì sọ fún mi pé, Ọmọ ènìyàn, gbójú sókè sí ìhà àríwá Èmi náà sì gbójú sókè sí ìhà àríwá mo sì rí ère tí ó ń mú ni jowú ní ẹnu ọ̀nà ibi pẹpẹ Ó sì wí fún mi pé, Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe-ohun ìríra ńlá tí ilé Ísírẹ́lì ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi Ṣùgbọ́n ìwọ ó tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù yí lọ Ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá Mo wò ó, mo sì rí ihò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri Nígbà náà ló sọ fún mi pé, Ọmọ ènìyàn, gbẹ́ inú ògiri náà, nígbà tí mo sì gbẹ́ inú ògiri, mo rí ìlẹ̀kùn kan Ó sì wí fún mi pé, Wọlé kí o rí ohun ìríra búburú tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ Mo wọlé, mo sì rí àwòrán oríṣìíríṣìí ẹranko tí ń fà nílẹ̀ àti àwọn ẹranko ìríra àti gbogbo òrìṣà ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí wọ́n yà sára ògiri Níwájú wọn ni àádọ́rin ọkùnrin tó jẹ́ àgbà ilé Ísírẹ́lì dúró sí, Jáásáníà ọmọ Sáfánì sì dúró sáàrin wọn Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde Ó sọ fún mi pé, Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì ń ṣe nínú òkùnkùn, olúkúlùkù ní yàrá òrìṣà rẹ̀ Wọ́n ní, Olúwa kò rí wa Olúwa ti kọ̀ ilé náà sílẹ̀   Ó tún sọ fún mi pé, Ìwọ yóò rí wọn tí wọ́n ń ṣe àwọn ohun mìíràn tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ Ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sí ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ fún Támúrì Ó sọ fún mi pé, Ṣé o rí báyìí, ọmọ ènìyàn Ìwọ yóò tún rí ìríra tó ga jù èyí lọ Ó mú mi wá sí ibi àgbàlá ilé Olúwa , lẹ́nu ọ̀nà tẹ́ḿpìlì Olúwa , wọn kọjú sí ìlà òòrùn, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún òòrùn ní apá ìlà òòrùn Ó sì wí fún mi, Ṣé o ti rí èyí ọmọ ènìyàn Ǹjẹ́ ohun kékéré ni fún ilé Júdà láti ṣe àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe níbi yìí Ṣé ó tún yẹ kí wọ́n fi ìwà ipá kún ilẹ̀ kí wọn sì máa mú mi bínú ní gbogbo ìgbà Wò wọn bi wọn se n fi ẹ̀ka wọn sínú inú wọn Nítorí náà, ń o fi ìbínú bá wọn wí n kò ní i dá wọn sí bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní fojú àánú wò wọ́n Bí wọ́n tilẹ̀ ń pariwo sí mi létí, n kò ní fetí sí wọn Wọ́n Pa Àwọn Abọ̀rìṣà Mo gbọ́ tó kígbe pé, Mú àwọn olùṣọ́ ìlú súnmọ́ ìtòsí, kí olúkúlùkù wọn mú ohun ìjà olóró lọ́wọ́ Lójú ẹsẹ̀ ni ọkùnrin mẹ́fà jáde láti ẹnu ọ̀nà òkè tó kọjú sí ìhà àríwá, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà olóró lọ́wọ́ wọn Ọkùnrin kan tó wọ aṣọ funfun lẹlẹ wa láàrin wọn, pẹ̀lú ohun ìkọ̀we lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ Gbogbo wọn sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ Ògo Ọlọ́run sì gòkè kúrò lórí Kérúbù, níbi tó wà tẹ́lẹ̀ lọ síbi ìloro tẹ́ḿpìlì Nígbà náà ni Olúwa pe ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun lẹlẹ tí ó sì ní ohun ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ Ó sì sọ fún un pé, La àárin ìlú Jérúsálẹ́mù já, kí o sì fi àmì síwájú orí gbogbo àwọn tó ń kẹ́dùn, tó sì ń sunkún nítorí ohun ìríra tí wọn ń ṣe láàrin rẹ̀ Bí mo ṣe ń fetí sí èyí, O tún sọ fún àwọn yòókù pé, Tẹ̀lé ọkùnrin náà lọ sáàrin ìlú láti pa láì dásí àti láì ṣàánú rárá Ẹ pa arúgbó àti ọ̀dọ́mọkùnrin, ẹ pa ọlọ́mọge, obìnrin àti ọmọ kékèké, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fọwọ́ kan àwọn tó ní àmì Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà tó wà níwájú tẹ́ḿpìlì Nígbà náà lo sọ fún wọn pé, Ẹ sọ tẹ́ḿpìlì náà di àìmọ́, kí òkú sì kún àgbàlá náà Ẹ lọ! Wọ́n jáde síta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa ènìyàn láàrin ìlú Èmi nìkan ló ṣẹ́kù nígbà tí wọ́n lọ pa àwọn ènìyàn mo dójú bolẹ̀, mo kígbe pé, Áà! Olúwa Ọlọ́run! Ìwọ yóò ha pa ìyókù Ísírẹ́lì pẹ̀lú dída ìbínú gbígbónà rẹ sórí Jérúsálẹ́mù Ó dá mi lóhùn pé, Ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì àti Júdà pọ gan an ni ilé wọn kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti àìsòótọ́ Wọ́n ní, Olúwa tí kọ ilẹ̀ náà sílẹ̀ Olúwa kò sì rí wa Nítorí náà, n kò ní wò wọ́n pẹ̀lú àánú n kò sì ní dá wọn sí, ṣùgbọ́n N ó dá ohun tí wọ́n ti ṣe padà sórí wọn Ọkùnrin aláṣọ funfun pẹ̀lú ohun ìkọ̀wé lẹ́gbẹ́ rẹ̀ sì wá jábọ̀ pé, Mo ti ṣe ohun tí o pa láṣẹ Sáírúsì Rán Àwọn Tí A Lé Sọnù Láti Padà Ní ọdún kìn-ní-ní Ṣáírúsì, ọba Páṣíà, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremáyà sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Ṣáírúsì ọba Páṣíà sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbégbé ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé Èyí ni ohun tí Sáírúsì ọba Páṣíà wí pé Olúwa , Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa fún un ní Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Júdà Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàárin yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Júdà, láti kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Ọlọ́run tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni tí ó lù ú bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran-ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá Ní àfikún, ọba Ṣáírúsì mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé Olúwa jáde wá, tí Nebukadinésárì ti kó lọ láti Jérúsálẹ́mù tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀ Ṣáírúsì ọba Páṣíà pàṣẹ fún Mítúrédátì olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣéṣíbásárì ìjòyè Júdà Èyí ni iye wọn Ọgbọ̀n àwo wúrà ẹgbẹ̀rún àwo fàdákà Àwo ìrúbọ fàdákà mọ́ kàndínlọ́gbọ̀n ọgbọ̀n àdému wúrà irinwó ó lé mẹ́wàá oríṣìí àdému fàdákà mìíràn ẹgbẹ̀rún kan àwọn ohun èlò mìíràn Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn ún-ó-lé-irinwó Ṣéṣíbáṣárì kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Bábílónì sí Jérúsálẹ́mù Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Ènìyàn Nígbà tí Ẹ́sirà ń gbàdúrà tí ó sì ń jẹ́wọ́, ti ó ń sunkún ti ó sì ń gbárayílẹ̀ níwájú ilé Ọlọ́run, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lí ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé pagbo yí i ká Àwọn náà ń sunkún kíkorò Nígbà náà ni Ṣékáníáyà ọmọ Jéhíélì, ọ̀kan lára ìran Élámù, sọ fún Ẹ́sírà pé, Àwa ti jẹ́ aláìsọ̀ọ́tọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì láàrin àwọn ènìyàn tí ó wà yí wa ká Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ náà, ìrètí sì wà fún Ísírẹ́lì Ní sinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a dá májẹ̀mú níwájú Ọlọ́run wa láti lé àwọn obìnrin yìí àti àwọn ọmọ wọn lọ Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn Ẹ́sírà Olúwa mi àti ti àwọn tí ó bẹ̀rù àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa Ẹ jẹ́ kí a ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin Dìde, nítorí, ọ̀rọ̀ tìrẹ ni èyí Gbogbo wà yóò wá pẹ̀lú rẹ, mú ọkàn le kí o sì ṣe é Nígbà náà ni Ésírà dìde, ó sì fi àwọn aṣíwájú àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Ísírẹ́lì sí abẹ́ ìbúra, láti ṣe ohun tí wọ́n dá lábàá Wọ́n sì búra Nígbà náà ni Ẹ́sírà padà sẹ́yìn kúrò níwájú ilé Ọlọ́run, ó sì lọ sí iyàrá Jéhóhánánì ọmọ Élíásíbù Nígbà tí ó wà níbẹ̀, kò jẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi, nítorí ó sì ń káàánú fún àìsòótọ́ àwọn ìgbèkùn Ìkèdè kan jáde lọ jákèjádò Júdà àti Jérúsálẹ́mù fún gbogbo àwọn ìgbèkùn láti péjọ sí Jérúsálẹ́mù Ẹnikẹ́ni tí ó ba kọ̀ láti jáde wá láàrin ọjọ́ mẹ́ta yóò pàdánù ohun ìní rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu àwọn ìjòyè àti àwọn àgbààgbà, àti pé a ó lé òun fúnraaarẹ̀ jáde kúrò láàrin ìpéjọpọ̀ àwọn ìgbèkùn Láàrin ọjọ́ mẹ́ta náà, gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà àti Bẹ́ńjámínì tí péjọ sí Jérúsálẹ́mù Ní ogúnjọ́ oṣù kẹ́sàn án, gbogbo àwọn ènìyàn jókòó sí ìta gbangba iwájú ilé Ọlọ́run, wọ́n wà nínú ìbànújẹ́ ńlá nítorí ọ̀ran yìí, àti nítorí òjò púpọ̀ tó tì rọ̀ Nígbà náà ni àlùfáà Ẹ́sírà dìde, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ̀yin ti ṣe àìsòótọ́, ẹ ti fẹ́ obìnrin àjèjì, ẹ ti dá kún ẹ̀bi Ísírẹ́lì Nísinsìnyìí, ẹ jẹ́wọ́ níwájú Olúwa , Ọlọ́run àwọn baba yín, kí ẹ sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn tí ó yí i yín ká àti láàrin àwọn ìyàwó àjèjì yín Àpéjọpọ̀ ènìyàn náà sì dáhùn lóhùn rara pé ohun tí ó sọ dára! A gbọdọ̀ ṣe bí o ti wí Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni ó wà ni ibi yìí ṣíbẹ̀ àkókò òjò ni àwa kò sì lè dúró níta Yàtọ̀ sí èyí, a kò le è yanjú ọ̀rọ̀ yìí láàrin ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ jọjọ lórí awọn nǹkan wọ̀nyí Jẹ́ kí àwọn ìjòyè wa ṣojú fún gbogbo ìjọ ènìyàn, lẹ́yìn náà, jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìlú wa tí ó ti fẹ obìnrin àjèjì wá ní àsìkò tí a yàn, pẹ̀lú àwọn àgbààgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ìbínú gíga Ọlọ́run wa lórí ọ̀rọ̀ yìí yóò fi kúrò ní orí wa Jónátanì ọmọ Ásáhélì àti Jáhéséáyà ọmọ Jíkífà nìkan pẹ̀lú àtìlẹyìn Mésísúlámù àti Ṣíábétaì ará Léfì, ni wọ́n tako àbá yìí Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n se fi ẹnu kò sí Àlùfáà Ẹ́sírà yan àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ìdílé kọ̀ọ̀kan, gbogbo wọn ni a sì mọ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, wọ́n jòkóó láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹjọ́ náà, Ní ọjọ́ kìn-ní-ní oṣù kìn-ní-ní ni wọn parí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì Lára ìran àwọn àlùfáà àwọn wọ̀nyí fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì Nínú ìran Jésíúà ọmọ Jósádákì, àti àwọn arákùnrin rẹ Mááséáyà, Élíásérì, Járíbù àti Gédáláyà Gbogbo wọn ni wọ́n Ṣe ìpinnu láti lé àwọn ìyàwó wọn lọ, wọ́n sì fi àgbò kan láàrin agbo ẹran lé lẹ̀ fún ẹ̀bi wọn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ Nínú ìran Ímérì Hánánì àti Ṣébádáyà Nínú ìran Hárímù Mááséáyà, Élíjà, Ṣíhémáyà, Jébíélì àti Úsáyà Nínú ìran Pásíhúrì Élíónáì, Mááséáyà, Ísímáílì, Nétaníẹ́lì, Jósábádì àti Élásáì Lára àwọn ọmọ Léfì Jósábádì, Ṣíhíméì, Kéláéáyà , Pétíáíyà, Júdà àti Élíásérì Nínú àwọn akọrin Élíásíbù Nínú àwọn asọ́nà Sálúmù, Télémù àti Úrì Àti lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tókù Nínú ìran Párósì Rámíáyà, Ísíáyà, Málíkíjà, Míjámínì, Éléásánì, Málíkíjà àti Bénáíyà Nínú ìran Élámù Mátaníáyà, Ṣékáríáyà, Jéhíélì, Ábídì, Jérémótì àti Élíjà Nínú àwọn ìran Ṣátítù Élíóénáì, Élísíbù, Mátaníáyà, Jérémótì, Ṣábádì àti Ásísà Nínú àwọn ìran Bébáì Jéhóánánì, Hánánáyà, Ṣábábáì àti Átaláì Nínú àwọn ìran Bánì Mésúlámì, Málúkì, Ádáyà, Jásílíbù, Ṣéálì àti Jérémótì Nínú àwọn Páhátì Móábù Ádínà, Kélálì, Bénáíáyà, Mááséíáyà, Mátítaníáyà, Bésálélì, Bínúì ati Mánásè Nínú àwọn ìran Hárímù Élíásérì, Ísíjà, Málíkíjà àti Ṣémáíáyà, Ṣíméínì, Bénjámínì, Málílúkì àti Ṣémáríà Nínú àwọn ìran Hásíúmù Mátíténáì, Mátítatítayà, Ṣábádì, Élífélétì, Jérémáì, Mánásè àti Ṣíméhì Nínú àwọn ìran Bánì Máádáì, Ámírámù, Úélì, Bénáíáyà, Bédéíáyà, Kélúhì, Fáníyà, Mérémótì, Élíásíbù, Mátítamáyà, Mátíténáì àti Jáásù Nínú àwọn ìran Bínúì Ṣíméhì, Ṣélémíáyà, Nátanì, Ádáyà, Mákánádébáì, Ṣásíáì, Ṣáráì, Ásárélì, Ṣélémíáyà, Ṣémáríàyà, Ṣálílúmì, Ámáríyà àti Jóṣẹ́fù Nínú àwọn ìran Nébò Jérélì, Mátítaíyà, Ṣábádì, Ṣábínà, Jádáì, Jóélì àti Bénáíáyà Gbogbo àwọn wọ̀nyí ló fẹ́ obìnrin àjèjì, àwọn mìíràn nínú wọn sì bi ọmọ ní ipaṣẹ̀ àwọn ìyàwó wọ̀nyí Àwọn Ìgbékùn Tí Ó Padà Wàyí o, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Júdà tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrin àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Bábílónì Iye àwọn ọkùnrin àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì Àwọn ìran Páróṣì jẹ́ ẹgbọ̀kànlá ó dín méjìdínlọ́gbọ̀n Ìran Ṣéfátíyà jẹ́ irinwó ó dín méjìdínlọ́gbọ̀n Ìran Árà jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó-dín-mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n Ìran Páhátì-Móábù jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rin-ó-le-méjìlá Ìran Élámì jẹ́ àádọ́tàlélẹ́gbẹ̀fà-ó-lé-mẹ́rin Ìran Ṣátù jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rún Ìran Ṣákáì jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin Ìran Bánì jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta-ó-lé méjì Ìran Bébáì jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mẹ́talélógún Ìran Áṣígádì jẹ́ ẹgbẹ̀fa-ó-lé méjìlélógún Ìran Ádóníkámù jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀tà-ó-lé mẹ́fà Ìran Bígífáyì jẹ́ ẹgbàá-ó-lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta Ìran Ádínì jẹ́ Àádọ́talénírínwó-ólé mẹ́rin Ìran Átérì nípaṣẹ̀ Heṣekáyà jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rin Ìran Bésáì jẹ́ Ọ̀rùndínnírínwó-ólé-mẹ́ta Ìran Jórà jẹ́ méjìléláàdọ́fà Ìran Hásúmì jẹ́ igba ólé mẹ́talélógún Ìran Gíbárì jẹ́ márùndínlọ́gọ́run Àwọn ọkùnrin Bétílẹ́hẹ́mù jẹ́ mẹ́talélọ́gọ́fà Ìran Nétófà jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́tà Ìran Ánátótì jẹ́ méjìdínládóje Ìran Áṣímáfétì jẹ́ méjìlélógójì Ìran Kíríátì Jéárímù, Éfírà àti Bérótì jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin-ólé-mẹ́ta Ìran Rámà àti Gébà jẹ́ ẹgbẹ̀ta-ó-lé mọ́kànlélógún Ìran Míkímásì jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà Ìran Bétélì àti Áì jẹ́ igba-ólé mẹ́talélógún Ìran Nébò jẹ́ méjìléláàdọ́ta Ìran Mágíbísì jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́jọ Ìran Élámù jẹ́ àádọ́ta lé-lẹ́gbẹ̀fà-ó-lé-mẹ́rin Ìran Hárímù jẹ́ ọ̀rìndínnírínwó Ìran Lódì, Hádídì àti Ónò jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-márùn-ún Ìran Jẹ́ríkò jẹ́ ọ̀tàdínnírínwó-ó-lé márùn-ún Ìran Ṣénà jẹ́ egbéjìdínlógún-ó-lé-ọgbọ̀n Àwọn Àlùfáà Àwọn Ìran Jédáíyà jẹ́ ogúndínlẹ́gbẹ̀rún ó-dín-méje Ìran Ímérì jẹ́ àádọ́ta lélẹ́gbẹ̀rún-ó-lé méjì Ìran Páṣúrì jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀fà ó-lé-méje Ìran Hárímù jẹ́ ẹgbẹ̀rin-ó-lé mẹ́tadínlógún Àwọn ará Léfì Àwọn Ìran Jésúà àti Kádíméì jẹ́ mẹ́rìnléláàdọ́rin Àwọn akọrin Àwọn Ìran Áṣáfì jẹ́ méjìdínláádóje Àwọn aṣọ́bodè Áwọn ara Ṣálúmì, Átérì, Tánímónì, Ákúbù, Hátítà àti Ṣóbíà jẹ́ mọ́kàndínlógóje Àwọn ìránṣẹ́ Tẹ́ḿpìlì Àwọn ìran Ṣíhà, Hásúfà, Tábáótì, Kérósì, Ṣíáhà, Pádónì, Lébánà, Hágábà, Ákúbù, Hágábì, Ṣálímáì, Hámánì, Gídélì, Gáhánì, Réáíyà, Résénì, Nékódà, Gásámù, Úṣà, Páséà, Bésáì, Áṣínà, Méúnímì, Néfúsímù, Bákíbúkì, Hákúfà, Háríhúrì Básílútì, Méhídà, Hárísà, Báríkósì, Ṣísérà, Témà, Nésíà àti Hátífà Àwọn Ìran tí ìránṣẹ́ Sólómónì Àwọn ìránṣẹ́ Ṣótaì, Hásóférétì, Pérúdà, Jálà, Dáríkónì, Gídè, Ṣépátíà, Hátílì, Pókérì-Háṣébáímì àti Ámì Àwọn ìrańṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn ìran àwọn ìranṣẹ́ Ṣólómónì jẹ́ irinwó-ó-dín-mẹ́jọ Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Télì-Mélà, Télì-Háríṣà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, ṣùgbọ́n wọn kò le fihàn pé àwọn ìdílé wọn ṣèẹ̀wá láti ìran Ísírẹ́lì Àwọn ìran Déláyà, Tóbíyà àti Nékódà jẹ́ àádọ́tàlélẹ́gbẹ̀ta-ó-lé-méjì Pẹ̀lú láti àárin àwọn àlùfáà Àwọn ìránṣẹ Hóbátà, Hákósì àti Báríṣíláì Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́ Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Úrímù àti Túmímù Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún-ó-lé-òjìdínnírinwó Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀ríndínlẹ́gbàárin-ó-dín mẹ́talélọ́gọ́ta ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin wọ́n ní igba akọrin ọkùnrin àti obìnrin Wọ́n ní ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin-ó-dín mẹ́rin ẹṣin ìbaka òjìlélúgba-ó-lé-márùn-ún Ràkúnmí jẹ́ irinwó-ó-lé-márùndínlógójì àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rínlélọ́gbọ̀n-ó-dín-ọgọ́rin Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá silẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ìwọ̀n dírámà wúrà, ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fàdákà àti ọgọ́rùn-ún ẹ̀wù àlùfáà Àwọn àlùfáà, àwọn ará Léfì, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn Títún Pẹpẹ Kọ́ Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, àwọn ènìyàn péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ní Jérúsálẹ́mù Nígbà náà ni Jéṣúà ọmọ Jósádákì àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Ṣérúbábélì ọmọ Ṣéálítíélì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ pẹpẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì láti rú ẹbọ sísun níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a ti kọ sínú ìwé òfin Mósè ènìyàn Ọlọ́run Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ẹ̀rù àwọn ènìyàn tí ó yí wọn ká ń bà wọ́n ṣíbẹ̀, wọ́n kọ́ pẹpẹ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì rú ọrẹ sísun lórí rẹ̀ sí Olúwa , ọrẹ àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ Nígbà náà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ, wọ́n ṣe àpèjọ àgọ́ ìpàdé pẹ̀lú iye ọrẹ sísun tí a fi lélẹ̀ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àti-gbà-dé-gbà, ẹbọ oṣù tuntun àti gbogbo àwọn ẹbọ fún gbogbo àpèjẹ tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa , àti àwọn tí a mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá fún Olúwa Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní rú ọrẹ sísun sí Olúwa , bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ì tí ì fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀ Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ní owó, wọ́n sì tún fi oúnjẹ, ohun mímu àti òróró fún àwọn ará Ṣídónì àti Tírè, kí wọ́n ba à le è kó igi Sídà gba ti orí omi òkun láti Lébánónì wá sí Jópà, gẹ́gẹ́ bí Sáírúsì ọba Páṣíà ti pàṣẹ Ní oṣù kejì ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti padà dé sí ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, Ṣérúbábélì ọmọ Ṣéálítíélì, Jéṣúà ọmọ Jósádákì àti àwọn arákùnrin yóòkù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà Wọ́n sì yan àwọn ọmọ Léfì tí ó tó ọmọ ogun ọdún sókè láti máa bojútó kíkọ́ ilé Olúwa Jéṣúà àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti Kádímíélì àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ Hénádádì àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn—gbogbo ará Léfì—parapọ̀ láti bojútó àwọn òṣìṣẹ́ náà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí í kíkọ́ ilé Ọlọ́run Nígbà tí àwọn ọ̀mọ̀lé gbé ìpìlẹ̀ ilé Olúwa kalẹ̀, àwọn àlùfáà nínú aṣọ iṣẹ́ àlùfáà wọn pẹ̀lú fèrè, àti àwọn ará Léfì pẹ̀lú Kíńbálì, dúró ní ipò wọn láti yin Olúwa , bí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ti fi lélẹ̀ Pẹ̀lú ìyìn àti ọpẹ́ ni wọ́n kọrin sí Olúwa Ó dára ìfẹ́ rẹ̀ sí Ísírẹ́lì dúró títí láé Gbogbo àwọn ènìyàn sì fi ohùn ariwo ńlá yin Olúwa , nítorí tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀ Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbà àlùfáà àti àwọn ará Léfì àti àwọn olórí ìdílé, tí ó ti rí tẹ́ḿpìlì Olúwa ti tẹ́lẹ̀, wọ́n sunkún kíkorò nígbà tí wọ́n rí ìpìlẹ̀ tẹ́ḿpìlì Olúwa yìí tí wọ́n fi lélẹ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ kígbe fún ayọ̀ Kò sí ẹni tí ó le mọ́ ìyàtọ̀ láàárin igbe ayọ̀ àti ẹkún, nítorí tí ariwo àwọn ènìyàn náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ Wọ́n sì gbọ́ igbe náà ní ọ̀nà jínjìn réré Àtakò Sí Àtúnkọ́ Ọ tẹ́ḿpìlì Nígbà tí àwọn ọ̀ta Júdà àti Bẹ́ńjámínì gbọ́ wí pé àwọn ìgbèkùn tí ó padà dé ń kọ́ tẹ́ḿpìlì fún Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Ṣérúbábélì àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé, wọ́n sì wí pé, Jẹ́ kí a bá a yín kọ́ nítorí pé, bí i ti yín, a ń wá Ọlọ́run yín, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà Ésáríhádónì ọba Ásíríà, tí ó mú wa wá síbi yìí Ṣùgbọ́n Ṣerubábélì, Jéṣúà àti ìyókù àwọn olórí àwọn ìdílé Ísírẹ́lì dáhùn pé, Ẹ kò ní ipa pẹ̀lú wa ní kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run wa Àwa nìkan yóò kọ́ ọ fún Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, bí Sáírúsì, ọba Páṣíà, ti pàṣẹ fún wa Nígbà náà ni àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú ọwọ́ àwọn ènìyàn Júdà rọ, wọ́n sì dẹ́rù bá wọ́n ní ti kíkọ́ ilé náà Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn láti ṣiṣẹ́ lòdì sí wọn àti láti sọ ète wọn di asán ní gbogbo àsìkò ìjọba Sáírúsì ọba Páṣíà àti títí dé ìgbà ìjọba Dáríúsì ọba Páṣíà Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ṣérísésì wọ̀n fi ẹ̀sùn kan àwọn ènìyàn Júdà àti Jérúsálẹ́mù Àti ní àkókò ìjọba Aritaṣéṣéṣì ọba Páṣíà, Bíṣílámì, Mítírédátì, Tábélì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ̀ rẹ̀ yóòkù kọ̀wé sí Aritaṣéṣéṣì A kọ ìwé náà ní ìlànà ìkọ̀wé Árámáíkì èdè Árámáíkì sì ní a fi kọ ọ́ Réhúmì balógun àti Ṣímíṣáì akọ̀wé jùmọ̀ kọ́ ìwé láti dojúkọ Jérúsálẹ́mù sí Aritaṣéṣéṣì ọba báyìí Réhúmì balógun àti Ṣímíṣáì akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tó kù—àwọn adájọ́ àti àwọn ìjòyè lórí àwọn ènìyàn láti Tírípólísì, Pásíà, Érékì àti Bábílónì, àwọn ará Élámì ti Súsà, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn tí ẹni ọlá àti ẹni ọ̀wọ̀ Áṣúríbánípálì lé jáde tí ó sì tẹ̀ wọ́n dó sí ìlú Samáríà àti níbòmíràn ní agbègbè e Yúfúrátè Sí ọba Aritaṣéṣéṣì, Lati ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin agbègbè Yúfúrátè Ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé àwọn ará Júù tí ó gòkè wá sọ́dọ̀ wa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti lọ sí Jérúsálẹ́mù wọ́n sì ń tún ìlú búburú àti ìlú ọlọ̀tẹ̀ ẹ nì kọ́ Wọ́n ń tún àwọn ògiri náà kọ́, wọ́n sì ń tún àwọn ìpìlẹ̀ náà ṣe Ṣíwájú síi, ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé tí a bá kọ́ ìlú yìí àti tí a sì tún àwọn ògiri rẹ̀ mọ, kò sí owó orí, owó òde tàbí owó ibodè tí a ó san, owó tí ó sì ń wọlé fún ọba yóò sì dínkù Nísinsìn yìí níwọ̀n ìgbà tí a ní ojúṣe sí ààfin ọba, kò sì bójúmu fún wa láti rí ìtàbùkù ọba, àwa ń rán iṣẹ́ yìí láti sọ fún ọba, kí a bá a lè ṣe ìwádìí ní inú ìwé ìrántí àwọn àṣíwájú rẹ̀ Nínú ìwé ìrántí wọn yìí, ìwọ yóò ríi wí pé, ìlú yìí jẹ́ ìlú aṣọ̀tẹ̀, oní wàhálà sí àwọn ọba àti àwọn ìgbèríko, ibi ìṣọ̀tẹ̀ láti ìgbà àtijọ́ Ìdí ni èyí tí a ṣe pa ìlú yìí run A fi dá ọba lójú wí pé tí a bá tún ìlú kọ́ àti ti àwọn ògiri rẹ̀ si di mímọ padà, kì yóò sì ohun ti yóò kù ọ́ kù ní agbégbé Yúfúrátè Ọba fi èsì yìí ránṣẹ́ padà Sí Réhúmì balógun, Ṣímíṣáì akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yóòkù tí ń gbé ní Samáríà àti ní òpópónà Yúfúrátè Ìkíní A ti ka ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa, a sì ti túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi Mo pa àṣẹ, a sì ṣe ìwádìí, nínú ìtàn ọjọ́ pípẹ́ àti ti ìsinsinyìí ti ìṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba pẹ̀lú, ó sì jẹ́ ibi ìṣọ̀tẹ̀ àti ìrúkèrúdò Jérúsálẹ́mù ti ní àwọn ọba alágbára tí ń jọba lórí gbogbo àwọn agbégbé Yúfúrátè, àti àwọn owó orí, owó òde àti owó ibodè sì ni wọ́n ń san fún wọn Nísinsìn yìí pa àṣẹ fún àwọn ọkùnrin yìí láti dá iṣẹ́ dúró, kí a má ṣe tún ìlú náà kọ títí èmi yóò fi pàṣẹ Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe àìkọbi-ara sí ọ̀rọ̀ yìí Èéṣe tí ìbàjẹ́ yóò fi pọ̀ sí i, sí ìpalára àwọn ọba Ní kété tí a ka ẹ̀dà ìwé ọba Aritaṣéṣéṣì sí Réhúmì àti Ṣímíṣáì akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, wọ́n yára lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú, wọ́n fi agbára mú wọn láti dáwọ́ dúró Báyìí, iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù wá sí ìdúró jẹ́ẹ́ títí di ọdún kejì ìjọba Dáríúsì ọba Páṣíà Lẹ́tà Táténáì sí Dáríúsì Nígbà náà wòlíì Hágáì àti wòlíì Ṣekaráyà, láti ìrán Ìdó, sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ará Júù ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù ní orúkọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bẹ lára wọn Nígbà náà Ṣerubábélì ọmọ Ṣéálítíélì àti Jéṣúà ọmọ Jóṣádákì gbáradì fún iṣẹ́ àti tún ilé Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù kọ́ Àwọn wòlíì Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́ Ní àkókò náà Táténáì, Baálẹ̀ ti agbègbè Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹgbẹ́gbẹ́ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn Wọ́n sì béèrè pé, Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún tẹ́ḿpìlì yìí kọ́ àti láti tún odi yìí mọ Wọ́n sì tún béèrè pé, Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí Ṣùgbọ́n ojú Ọlọ́run wọn wà lára àwọn àgbààgbà Júù, wọn kò sì dá wọn dúró tí tí ìròyìn yóò fi dè ọ̀dọ̀ Dáríúsì kí wọ́n sì gba èsì tí à kọ sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Tétanáì, olórí agbégbé Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ ẹ wọn Àwọn olóyè ti agbégbé Yúfúrátè, fi ránṣẹ́ sí ọba Dáríúsì Ìròyìn tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i kà báyìí pé Sí ọba Dáríúsì Àlàáfíà fún un yín Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Júdà, sí tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run alágbára Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńlá ńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsinmi, ó sì ń ní ìtẹ̀ṣíwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn A bi àwọn àgbààgbà, a sì fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò pé, Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún ilé Olúwa yìí kọ́ àti láti tún odi rẹ̀ mọ A sì tún bèèrè orúkọ wọn pẹ̀lú, kí a lè kọ àwọn orúkọ àwọn olórí wọn silẹ̀ kí ẹ ba à le mọ ọ́n Èyí ni ìdáhùn tí wọ́n fún wa Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, àwa sì ń tún tẹ́ḿpìlì ilé Olúwa tí a ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kọ́, èyí tí ọba olókìkí kan ní Ísírẹ́lì kọ́, tí ó sì parí i rẹ̀ Ṣùgbọ́n nítorí tí àwọn baba wa mú Ọlọ́run ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadinésárì ti Kálídéà, ọba Bábílónì lọ́wọ́, ẹni tí ó run tẹ́ḿpìlì Olúwa yìí tí ó sì kó àwọn ènìyàn náà padà sí Bábílónì Ṣùgbọ́n ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba Ṣáírúsì ọba Bábílónì, ọba Ṣáírúsì pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́ Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni tí ó lọ bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran-ọ̀sìn pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn-án lọ́wọ́ fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù Kí wọn sì mú wá sí tẹ́ḿpílì ní Bábílónì Nígbà náà ọba Sáírúsì kó wọn fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣesibásárì, ẹni tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí i Baálẹ̀, ó sì sọ fún un pé, Kó àwọn ohun èlò yìí kí o lọ, kí o sì kó wọn sí inú ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, pẹ̀lú kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ipò o rẹ̀ Nígbà náà ni Ṣesibásásárì náà wá, ó sí fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tí ó wá ní Jérúsálẹ́mù lẹ́lẹ̀, láti ìgbà náà àní títí di ìsínsìn yìí ni o ti n bẹ ní kíkọ́ ṣùgbọ́n, kò sí tí ì parí tán Nísinsìn yìí tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí ní ilé ìṣúra ọba ní Bábílónì láti rí bí ọba Ṣáírúsì fi àṣẹ lélẹ̀ lóòótọ́ láti tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́ ní Jérúsálẹ́mù Nígbà náà jẹ́ kí ọba kó fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa Dáríúsì Rí Ìwé Àṣẹ Sáírúsì Nígbà náà ni ọba Dáríúsì pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí-nǹkan-pamọ́-sí ní ilé ìṣúra ní Bábílónì A rí ìwé kíká kan ní Ékíbátanà ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódí agbégbé Médíà, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀ Ìwé ìrántí Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba Ṣáírúsì, ọba pa àṣẹ kan nípa tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù Jẹ́ kí a tún tẹ́ḿpìlì ibi tí a ti ń rú onírúurú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ní gíga àti àádọ́rùn-ún ẹsẹ̀ bàtà ní fífẹ̀, pẹ̀lú ìpele òkúta ńlá ńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ìpele pákó kan, kí a san owó rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra ọba Sì jẹ́ kí wúrà àti àwọn ohun èlò fàdákà ti ilé Ọlọ́run, tí Nebukadinésárì kó láti ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù tí ó sì kó lọ sí Bábílónì, di dídá padà sí àyè wọn nínú tẹ́ḿpìlì ní Jérúsálẹ́mù kí a kó wọn sí inú ilé Ọlọ́run Nítorí náà, kí ìwọ, Táténíà Baálẹ̀ agbègbè Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ yín, àwọn ìjòyè ti agbègbè náà, kúrò níbẹ̀ Ẹ fi iṣẹ́ ilé Ọlọ́run yìí lọ́rùn sílẹ̀ láì díi lọ́wọ́ Ẹ jẹ́ kí Baálẹ̀ àwọn Júù àti àwọn àgbààgbà Júù tún ilé Ọlọ́run yín kọ́ sí ipò rẹ̀ Síwájú sí i, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe fún àwọn àgbààgbà Júù wọ̀nyí lórí kíkọ́ ilé Ọlọ́run yìí Gbogbo ìnáwó àwọn ọkùnrin yìí ni kí ẹ san lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lára ìṣúra ti ọba, láti ibi àkójọpọ̀ owó ìlú ti agbègbè Yúfúrátè kí iṣẹ́ náà má bà dúró Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn akọ ọ̀dọ́ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́ àgùntàn fún ọrẹ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, ìfiyàn bí àwọn àlùfáà ní Jérúsálẹ́mù ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láì yẹ̀ Kí wọn lè rú àwọn ẹbọ tí ó tẹ́ Ọlọ́run ọ̀run lọ́rùn kí wọ́n sì gbàdúrà fún àlàáfíà ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a si fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀ èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹ́ḿpìlì yìí tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù ṣubú Èmi Dáríúsì n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímú ṣẹ láì yí ohunkóhun padà Nígbà náà, nítorí àṣẹ tí ọba Dáríúsì pa, Táténáì, Baálẹ̀ ti agbégbé Yúfúrátè, àti Ṣétarì-Bóṣénáì pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn pa á mọ́ láì yí ọ̀kan padà Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbààgbà Júù tẹ̀ṣíwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hágáì àti wòlíì Ṣekaráyà, ìran Ídò Wọ́n parí kíkọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti àwọn àṣẹ Ṣáírúsì, Dáríúsì àti Aritaṣéṣéṣì àwọn ọba Páṣíà pọ̀ A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Ádárì ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dáríúsì Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì—àwọn ìkógun, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù , ọgọ́rùn-ún méjì àgbò àti ọgọ́run mẹ́rin akọ ọ̀dọ́ àgùntàn , àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì, obúkọ méjìlá , ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpínsọ́wọ́ àti àwọn Léfì sì ẹgbẹẹgbẹ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mósè Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nísàn , àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́ Àwọn ará Léfì pa ọ̀dọ́ àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó ti dé láti ìgbèkùn jẹ ẹ́ lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ti ya ara wọn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àìmọ́ ti àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti wá Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ Búrẹ́dì tí kò ní Yíìsìtì pẹ̀lú àjẹtì àkàrà Nítorí tí Olúwa ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba Ásíríà padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì Ésírà Wá Sí Jérúsálẹ́mù Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ní àkókò ìjọba ọba Aritaṣéṣéṣì ní Páṣíà, Ẹ́sírà ọmọ Ṣéráíyà, ọmọ Ásáríyà, ọmọ Hílíkíyà, Ọmọ Ṣálúmù, ọmọ Ṣádókù, ọmọ Áhítúbì, ọmọ Ámáríyà, ọmọ Ásáríyà, ọmọ Méráíótù, ọmọ Ṣéráháyà, ọmọ Húsì, ọmọ Búkì, ọmọ Ábísúà, ọmọ Fínéhásì, ọmọ Élíásérì, ọmọ Árónì olórí àlùfáà— Ẹ́sírà yìí gòkè wá láti Bábílónì Olùkọ́ tí ó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òfìn Mósè, èyí tí Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti fi fún wọn Ọba sì fi gbogbo ohun tí ó béèrè fún un, nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára rẹ̀ Ní ọdún keje ọba Aritaṣéṣéṣì díẹ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà àti àwọn tí ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì náà gòkè wá sí Jérúsálẹ́mù Ní oṣù kánùn-ún ọdún keje ọba yìí ni Ẹ́sírà dé sí Jérúsálẹ́mù Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ láti Bábílónì ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ó sì dé Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run rẹ̀ wà ní ara rẹ̀ Ẹ́sírà ti fi ara rẹ̀ jìn fún kíkọ́ àti pípa òfin Olúwa mọ́, ó sì ń kọ́ òfin àti ìlànà Mósè ní Ísírẹ́lì Èyí ni ẹ̀dà lẹ́ta ti ọba Aritaṣéṣéṣì fún àlùfáà Ẹ́sírà olùkọ́ni, ẹni tó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ òfin àti ìlànà Olúwa fún Ísírẹ́lì Aritaṣéṣéṣì, ọba àwọn ọba, Sí àlùfáà Ẹ́sírà, olùkọ́ni ni òfin Ọlọ́run ọ̀run Àlàáfíà Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkòóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jérúsálẹ́mù lè tẹ̀lé ọ lọ Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèjè rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Júdà àti Jérúsálẹ́mù Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jérúsálẹ́mù, pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ lè rí ní agbègbè ìjọba Bábílónì àti àwọn ọrẹ àtinúwá àwọn ènìyàn àti ti àwọn àlùfáà fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run wọn ní Jérúsálẹ́mù Pẹ̀lú owó yìí, rí i dájú pé ó ra àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ , àti ọrẹ ohun mímu, kí ìwọ kí ó fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ ní Jérúsálẹ́mù Ìwọ àti àwọn Júù arákùnrin rẹ lè fi èyí tó kù fàdákà àti wúrà ṣe ohunkóhun tí ó bá dára lójú yín, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run yín Kó gbogbo ohun èlò tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ fún Ọlọ́run Jérúsálẹ́mù fún ìsìn nínú tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ Ohunkóhun mìíràn tí o bá nílò fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ tí ó sì ní láti pèsè, o lè mú u láti inú ìṣúra ọba Èmi, ọba Aritaṣéṣéṣì, pàṣẹ fún gbogbo olùtọ́jú ilé ìṣúra agbègbè Yúfúrátè láìrójú láti pèṣè ohunkóhun tí àlùfáà Ẹ́sírà, olùkọ́ni ní òfin Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè lọ́wọ́ yín tó ọgọ́run kan talẹ́ntì fàdákà, ọgọ́rùn-ún kan òṣùwọ̀n jéró, ọgọ́rùn-ún gálọ́ọ̀nù wáìnì, ọgọ́rùn-ún gálọ́ọ̀nù òróró olífì, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ̀ Ohunkóhun tí Ọlọ́run ọ̀run bá fẹ́, jẹ́ kí ó di ṣíṣe ní pípé fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ọ̀run Èéṣe tí ìbínú yóò ṣe wá sí agbégbé ọba àti sí orí àwọn ọmọ rẹ̀ Ìwọ sì ní láti mọ̀ pé ìwọ kò ní àṣẹ láti sọ sisán owó orí, owó òde tàbí owó bodè di dandan fún àwọn àlùfáà, àwọn Léfì, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà, àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì tàbí àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn nínú ilé Ọlọ́run yìí Ìwọ Ẹ́sírà, ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n Ọlọ́run rẹ̀, èyí tí ó ní, yan àwọn adájọ́ àgbà àti àwọn onídàájọ́ láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn agbègbè—Yúfúrátè—gbogbo àwọn tí ó mọ òfin Ọlọ́run rẹ Ìwọ yóò sì kọ́ ẹnikẹ́ni tí kò mọ̀ àwọn òfin náà Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe ìgbọ́ràn sí òfin Ọlọ́run rẹ àti sí òfin ọba ní ó gbọdọ̀ kú tàbí kí a lé e jáde tàbí kí a gbẹ́sẹ̀ lé ẹrù rẹ̀ tàbí kí a sọ ọ́ sínú ẹ̀wọ̀n Olùbùkún ni Olúwa , Ọlọ́run àwọn baba wa, ẹni tí ó fi sí ọkàn ọba láti mú ọla wá sí ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù ní ọ̀nà yìí Ẹni tí ó jẹ́ kí ojú rere rẹ̀ tàn kàn mí níwájú ọba àti àwọn olùbádámọ̀ràn àti ní iwájú àwọn alágbára ìjòyè ọba Nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára mi, mo mú ọkàn le, mo sì kó àwọn olórí jọ láàrin àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì láti gòkè lọ pẹ̀lú mi Olórí Àwọn Ìdílé Tí ó Padà Pẹ̀lú Ẹ́sírà Wọ̀nyí ni àwọ̀n olórí ìdílé àti àwọn tí ó fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn tì wọn gòkè pẹ̀lú mi làti Bábílónì ní àkókò ìjọba Aritaṣéṣéṣì ọba Nínú àwọn ọmọ Fínéhásì, Gásómù nínú àwọn ọmọ Ítamárì, Dáníẹ́lì nínú àwọn ọmọ Dáfídì, Hátúsì, nínú àwọn ọmọ Ṣekaníáyà nínú àwọn ọmọ Párósì, Ṣekaríáyà, àti pé àádọ́jọ ọkùnrin fi orùkọ sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ nínú àwọn ọmọ Pahati-Móábù, Elehóénáyì ọmọ Seraíyà àti àwọn igba ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ṣátù, Ṣekaníáyà ọmọ Jahasíélì àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ádínì, Ébédì ọmọ Jónátanì, àti àádọ́ta ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọmọ Élámù, Jésáíyà ọmọ Ataláyà àwọn àádọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ṣéfátayà, Ṣébádáyà ọmọ Míkẹ́lì, àti ọgọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọmọ Jóábù, Ọbádáyà ọmọ Jéhíélì àti ogun-ó-lugba-ó-din méjì ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọmọ Bánì, Ṣélómútì ọmọ Jósífáyà àti ọgọ́jọ 160 ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọmọ Bébáì, Sakaráyà ọmọ Bébáì àti ọkúnrin 45 méjìdínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ásígádì, Johánánì ọmọ Hákátanì, àti àádọ́fà ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ádóníkámù, àwọn ti ó gbẹ̀yìn, tì orùkọ wọn ń jẹ̀ Élífélétì, Jéúélì àti Ṣémáyà, àti ọgọ́ta ọkúnrin pẹ̀lú wọn Nínú àwọn ọmọ Bígífáyì, Hútayì àti Ṣákúrì, àti àádọ́rin 70 ọkúnrin pẹ̀lú wọn Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń ṣàn lọ sí Áháfà, a pàgọ́ síbẹ̀ fùn odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárin àwọn ènìyàn àti àárin àwọn àlùfáà, ń kò ri ọmọ Léfì kankan níbẹ̀ Nígbà náà ni mo pe Élíásérì, Áríélì, Ṣemanáyà, Elinátanì, Járíbù, Elinátánì, Nátanì, Ṣakaráyà, àti Mésúlámù, ti wọ̀n jẹ̀ olórí, àti Jóíáríbù àti Elinátanì ti wọ̀n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀, mo rán wọn sí Ídò, tí ó wà ní ibi ti a ń pè ni Kásífíà, mo sì sọ ohun ti wọn yóò sọ fun Ídò àti àwọn arakunrin rẹ̀ ti wọn jẹ́ òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì ní Kásífíà fún wọn, pé, kí wọn mú àwọn ìránṣẹ́ wá fún wa fún ilé Ọlọ́run wa Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n sì mú Ṣérébáyà wá fún wa, ẹni tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ìran Máhílì ọmọ Léfì, ọmọ Ísírẹ́lì, àti àwọn ọmọ Ṣérébáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjìlélógún Àti Ásábáyà, pẹ̀lú Jésáíyà láti ìran Mérárì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ wọ́n jẹ́ ogún ọkùnrin Wọ́n sì tún mú ọ̀kànlénígba àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì wá-àwọn ènìyàn tí Dáfídì àti àwọn ìjòyè rẹ gbé kalẹ̀ láti ràn àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́ Gbogbo wọn ni a ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn Níbẹ̀, ní ẹ̀bá odò Áháfà, mo kéde ààwẹ̀, kí a ba à le rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run kí a sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìrìnàjò àìléwu fún wa àti àwọn ọmọ wa àti fún gbogbo ohun ìní wa Mo tijú láti béèrè lọ́wọ́ ọba fún àwọn jagunjagun orí ilẹ̀, àti ti orí ẹsin láti dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ní ọ̀nà wa, nítorí àti sọ fún ọba pé, Ọwọ́ àánú Ọlọ́run wà ní ara gbogbo ẹni tí ó gbé ojú sókè sí i, ṣùgbọ́n ìbìnú ńlá rẹ wà lórí ẹni tó kọ̀ sílẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni a sì gbààwẹ̀, a sì bẹ̀bẹ̀ fún èyí lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, òun sì gbọ́ àdúrà wa Nígbà náà ni mo yà àwọn àlùfáà tó jẹ́ aṣáájú méjìlá sọ́tọ̀, pẹ̀lú Ṣérébáyà, Hásábáyà àti mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn, Mo sì fi òṣùwọ̀n wọn ọrẹ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀, awọn ìjòyè àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà níbẹ̀ gbe fi sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run wa Mo fi òsùwọ̀n wọn ẹgbẹ̀talẹ̀láàdọ́ta talẹ́ńtì sílifà, àti ohun èlò fàdákà tí ó wọn ọgọ́rùn ún talẹ́ńtì, talẹ́ńtì wúrà ogún bóòlù wúrà tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún dárìkì, àti ohun èlò idẹ dáradára méjì ti ó ni iye lórí, bí i wúrà Mo wí fún wọn pé, Ẹ̀yin àti àwọn ohum èlò wọ̀nyí ni a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa Sílífà àti wúrà sì jẹ́ ọrẹ àtinúwá sí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín Tọ́jú wọn dáradára títí ìwọ yóò se fi òṣùwọ̀n wọ̀n wọ́n jáde kúrò ni ilé Olúwa ni Jérúsálẹ́mù ní iwájú àwọn aṣáájú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti ní iwájú olórí ìdílé gbogbo ni Ísírẹ́lì Nígbà náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì gba fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ́ ti a ti wọ̀n jáde fún kíkó lọ sí ilé Ọlọ́run wa ní Jérúsálẹ́mù Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kìn-ín-ní ni a gbéra kúrò ní ẹ̀bá odò Áháfà láti lọ sí Jérúsálẹ́mù Ọwọ́ Ọlọ́run wa wà lára wa, ó sì dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta àti àwọn adigunjalè ní ọ̀nà wa Bẹ́ẹ̀ ni a gúnlẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù, nibi ti a ti sinmi fún ọjọ́ mẹ́ta Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn ohun èlò fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ lé àlùfáà Mérémótì ọmọ Úráyà lọ́wọ́, láti inú ilé Ọlọ́run wa, Élíásérì ọmọ Fínéhásì wà pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì Jósábádì ọmọ Jésíúà àti Núádáyà ọmọ Bínúì wà níbẹ̀ pẹ̀lú Gbogbo nǹkan ni a kà tí a sì wọ̀n, gbogbo iye ìwọ̀n ni a sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé ìgbà náà Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn tí o ti pada láti ilẹ̀ àjèjì rú ẹbọ ọrẹ sísun sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì akọ màlúù méjìlá fún gbogbo Ísírẹ́lì, àádọ́rùn-ún-o-lé-mẹ́ta akọ ọdọ àgùntàn àti òbúkọ méjìlá fún ọrẹ sísun sí Olúwa Wọ́n sì jíṣẹ́ àṣẹ ọba fún àwọn ìjòyè àti àwọn baálẹ̀ agbègbè Éúfúrétè, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn àti ilé Ọlọ́run nígbà náà Àdúrà Ẹ́sírà Nípa Ìgbéyàwó Pẹ̀lú Àwọn Àjòjì Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá wọ́n sì wí pé, Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, ti ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ọmọ Kénánì, Hítì, Pérísì, Jébúsì, Ámónì, Móábù Éjíbítì àti Ámórì Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tó kù yọ nínú hihu ìwà Àìsòótọ́ Nígbà tí mo gbọ́ èyí, mo fa àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi ya, mo ja irun orí àti irungbọ̀n mi, mo sì jókòó ní ìbànújẹ́ Nígbà náà ni gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì kó ara wọn jọ yí mi ká nítorí àìsòótọ́ àwọn ìgbékùn yìí Èmi sì jókòó níbẹ̀ ní ìbànújẹ́ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ̀ Ní ìgbà tí o di àkókò ìrúbọ àṣálẹ̀, mo dìde kúrò nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn mi, pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi yíya ní ọrùn mi, mo kúnlẹ̀ lórí eékún mi méjèèjì, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi méjèèjì sí Olúwa Ọlọ́run mi Mo sì gbàdúrà Ọlọ́run mi, ojú tì mí gidigidi kò sì yá mi lórí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, Ọlọ́run mi, nítorí ẹṣẹ̀ wá ga ju orí wa lọ, àwọn àìṣedéédéé wa sì ga kan àwọn ọ̀run Láti ìgbà àwọn baba wá, títí di ìsinsin yìí, àìṣedéédéé wa ti pọ̀ jọjọ Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwa àti àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa ni a ti sọ di ẹni idà àti ìgbèkùn, ìkógun àti ẹni ẹ̀ṣín lọ́wọ́ àwọn àjèjì ọba, bí ó ti rí lónìí Ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí, fún ìgbà díẹ̀, Olúwa Ọlọ́run ti fi àánú rẹ̀ dá àwa tí ó sẹ́kù sí tí ó sì fún wa ni ibi pàtàkì nínú ibi mímọ́ rẹ̀, nítorí náà Ọlọ́run wa ti fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú wa àti ìgbé ayé túntún kúrò nínú ìgbékùn wa Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa jẹ́ ẹrú, Ọlọ́run wa kò fi wa sílẹ̀ nínú ìgbèkùn wa Ó ti fi àánú hàn fún wa ni iwájú àwọn ọba Páṣíà Ó ti fún wa ní ìgbé ayé tuntún láti tún odi ilé Ọlọ́run wa mọ, kí a sì tún àwókù rẹ̀ mọ, ó sì fi odi ààbò fún wa ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, kí ni àwa yóò wí lẹ́yìn èyí Ìwọ Ọlọ́run wa, nítorí tí àwa kò pa àṣẹ rẹ mọ́ èyí tí ìwọ fún wa láti ipaṣẹ̀ àwọn wòlíì ìrànṣẹ rẹ, nígbà ti ìwọ wí pé ilẹ̀ ti ẹ̀yin ń wọ̀ lọ láti lọ gbà jẹ́ ilẹ̀ tí ó di àìmọ̀ pẹ̀lú ìwà ìbàjẹ́ àwọn ènìyàn rẹ, nípa ṣíṣe ohun ìríra ilẹ̀ náà ti kún fún ohun àìmọ́ láti igun kan dé ìkejì Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbà-kí-gbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì jẹ ohun dáradára ilẹ̀ náà, kí ẹ sì fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayé rayé Ohun tí ó ti sẹlẹ̀ sí wa jẹ́ ayọrísí iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi-ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wa, ṣíbẹ̀, Ọlọ́run wa, ìjìyà ti ìwọ fún wa kéré si ìjìyà tí ó yẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá, ìwọ sì fún wa ní àwọn ènìyàn tó sẹ́kù bí èyí Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa tún yẹ̀ kúrò nínú àṣẹ rẹ, kí a sì máa ṣe ìgbéyàwó papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣe onírúurú ohun ìríra báyìí Ṣe ìwọ kò ní bínú sí wa láti pa wá run tí kì yóò sẹ́ ku ẹnìkẹ́ni tí yóò là Ìwọ Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ìwọ jẹ́ olódodo O dá wa sí lónìí bí àwọn tí ó ṣẹ́kà Àwa nìyí níwájú rẹ nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí rẹ̀ ẹyọ ẹnìkan kò lè dúró níwájú rẹ Pọ́ọ̀lù Àpósítélì Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jésù Kírísítì àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi, Sí àwọn ìjọ ní Gálátíà Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jésù Kírísítì Olúwa, ẹni tí ó fí òun tìkararẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa, ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé Àmín Ẹnu yà mi nítorí tí pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kírísítì, sí ìyìn rere mìíràn èyí tí kì í ṣe ìyìn rere rárá Ìdánilójú wà pé àwọn kan wà tí wọ́n ń sì yín lọ́nà, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìyìn rere Kírísítì padà Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí ańgẹ́lì kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìyìn rere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé! Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsinyìí pé Bí ẹnìkan bá wàásù ìyìn rere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé! Ǹjẹ́ nísinsìnyìí ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kírísítì Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ará, pé ìyìn rere tí mo tí wàásù kì í ṣe láti ipa ènìyàn N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jésù Kírísítì Nítorí ẹ̀yin ti gbúrò ìwà-ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́ Mo sì ta ọ̀pọlọ́pọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrin àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọpọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wú Ọlọ́run ẹni tí ó yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi wá, tí ó sì pé mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ Láti fi ọmọ rẹ̀ hàn nínú mi, kì èmi lè máa wàásù rẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà èmi kò wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gòkè lọ sì Jerúsálémù tọ àwọn tí í ṣe Àpósítélì ṣáájú mi ṣùgbọ́n mo lọ sí Árábíà, mo sì tún padà wá sí Dámásíkù Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, nígbà náà ni mo gòkè lọ sì Jerúsálémù láti lọ kì Pétérù, mo sì gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, Èmi kò ri ẹlòmíràn nínú àwọn tí ó jẹ́ Àpósítélì, bí kò ṣe Jákọ́bù arákùnrin Olúwa Nǹkan tí èmi ń kọ̀wé sí yín yìí kíyèsí i, níwájú Ọlọ́run èmi kò ṣèké Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Síríà àti ti Kílíkáíà Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kírísítì ni Jùdíà Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsìn yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi Àwọn Àpósítélì Tẹ́wọ́ Gba Pọ́ọ̀lù Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, ni mo tún gòkè lọ sì Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú Bánábà, mo sì mú Títù lọ pẹ̀lú mi Mo gòkè lọ ní ìbámu ìfihàn, mo gbé ìyìn rere náà tí mo ń wàásù láàrin àwọn aláìkọlà kalẹ̀ níwájú wọn Ṣùgbọ́n mo se èyí ní ìkọ̀kọ̀ fún àwọn tí ó jẹ́ olùdarí, ni ẹ̀rù pé mo ń sáré tàbí mo tí sáré ìje mi lásán Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Títù tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Gíríkì láti kọlà Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárin wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kírísítì Jésù, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè Fún wọn, a kò tilẹ̀ fí ààyè sílẹ̀, nígbà kan rárá kí òtítọ́ ìyìn rere lè máa wà títí pẹ̀lú yin Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn já sí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi Ọlọ́run kò fi bí ẹnìkẹ́ni se rí se ìdájọ́ rẹ̀—àwọn eniyan yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọn rí i pé a tí fi ìyìn rere tí àwọn aláìkọlà le mi lọ́wọ́, bí a tí fi ìyìn rere tí àwọn onílà lé Pétérù lọ́wọ́ Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránsẹ Pétérù gẹ́gẹ́ bí Àpósítélì sí àwọn Júù, òun kan náà ni ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránsẹ mi gẹ́gẹ́ bí Àpósítélì sí àwọn aláìkọlà Jákọ́bù, Pétérù, àti Jòhánù, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ̀n, fún èmi àti Bánábà ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fe tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù Ohun gbogbo tí wón bèèrè fún ni wí pé kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan-an tí mo ń làkàkà láti ṣe Ṣùgbọ́n nígbà tí Pétérù wá sí Ańtíókù, mo ta kò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ ẹni tí à bá báwí Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jákọ́bù wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fà sẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lati jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Bánábà lọnà Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédéé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìyìn rere, mo wí fún Pétérù níwájú gbogbo wọn pé, Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn aláìkọlà, è é ṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn aláìkọlà láti máa rìn bí àwọn Júù Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀, Tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì, àní àwa pẹ̀lú gbà Jésù Kírísítì gbọ́, kí a báa lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kírísítì, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kírísítì, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ́lú jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kírísítì ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí Kí a má rí ì! Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fí ara mi hàn bí arúfin Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láàyè sí Ọlọ́run A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kírísítì, èmí kò sì wà láàyè mó, ṣùgbọ́n Kírísítì ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láàyè nínú ara, mo wà láàyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkararẹ̀ fún mi Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apákan nítorí pé bí a bá le ti pasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kírísítì kú lásán Igbàgbọ́ Tàbí Ìwòfífí Òfin Ẹ̀yin aláìnírònú ará Gálátíà! ta ní ha tàn yín jẹ, kí ẹ̀yin má ṣe gba òtítọ́ gbọ́ Ní ojú ẹni tí a fi Jésù Kírísítì hàn gbangba láàrin yín ni ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú Kìkì èyí ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ yín Nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ̀yin gba Ẹ̀mi bí, tàbí nípa ìgbọ́ràn pẹ̀lú ìgbàgbọ́ Báyìí ni ẹ̀yin ṣe gọ̀ tó bí Lẹyin tí ẹ bẹ̀rẹ̀ nípa tí Ẹ̀mí, a há ṣe yín pé nísinsìnyìí nípa tí ara Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán Bí ó bá ṣe pé nítoótọ́ lásán ni Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́-ìyanu láàrin yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ sí ohun tí ẹ gbọ́ Gẹ́gẹ́ bí Ábúráhámù Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí fún un ní òdodo Ẹ jẹ́ kí ó yé é yín nígbà náà pé, àwọn ti ó gbàgbọ́, àwọn náà ní í ṣe ọmọ Ábúráhámù Bí ìwé-mímọ́ sì tí wí tẹ́lẹ̀ pé, Ọlọ́run yóò dá aláìkọlà láre nípa ìgbàgbọ́, ó tí wàásù ìyìn rere ṣáájú fún Ábúráhámù, ó ń wí pé, Nínú rẹ̀ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí i ṣe tí ìgbàgbọ́ jẹ́ ẹni alábùkúnfún pẹ̀lú Ábúráhámù olódodo Nítorí pé iye àwọn tí ń bẹ ni ipa iṣẹ́ òfin ń bẹ lábẹ́ ègún nítorí tí a tí kọ ọ́ pé, Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí kò dúró nínú ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé òfin láti máa ṣe wọ́n Nítorí ó dánilójú pé, a kò dá ẹnìkẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òfin nítorí pé, olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ Òfin kì í sì í ṣe ti ìgbàgbọ́ ṣùgbọ́n Ẹnikẹ́ni tí ń se wọn yóò yè nípaṣẹ̀ wọn Kírísítì ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi Kí ìbùkún Ábúráhámù ba à lè wá sórí àwọn aláìkọlà nípa Kírísítì Jésù kí àwa ba à lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa ìgbàgbọ́ Ará, èmi ń ṣọ̀rọ̀ bí ènìyàn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé májẹ̀mú ènìyàn ni, ṣùgbọ́n bí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò sí ẹni tí ó lè sọ ọ́ di asán, tàbí tí ó lè fi kún un mọ́ Ǹjẹ́ fún Ábúráhámù àti fún irú ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà Òun kò ṣe wí pé, Àti fún irú-ọmọ rẹ̀, èyí tí í ṣe Kírísítì Èyí tí mò ń wí ni pé Májẹ̀mu tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣáájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀n-lé-nírinwó ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, tí à bá fi mú ìlérí náà di aláìlágbára Nítorí bí ìjogún náà bá ṣe ti òfin kì í ṣe ti ìlérí mọ́ ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í fún Ábúráhámù nípa ìlérí Ǹjẹ́ kí há ni òfin A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé a sì tipaṣẹ̀ àwọn áńgẹ́lì lànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá Ǹjẹ́ alárinà láàrin ẹgbẹ́ tí ó ju ọ̀kan ṣoṣo lọ ṣùgbọ́n ọ̀kan ni Ọlọ́run Nítorí náà òfín ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí Kí a má rí i Nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà Ṣùgbọ́n ìwé-mímọ́ ti sé gbogbo nǹkan mọ́ sábẹ́ ẹṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì fún àwọn tí ó gbàgbọ́ Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fi hàn Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùkọ́ni láti múni wá sọ́dọ̀ Kírísítì, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùkọ́ni mọ́ Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Jésù Nítorí pé iye ẹ̀yin tí a ti baptisti sínú Kírísítì ti gbé Kírísítì wọ̀ Kò le sí Júù tàbí Gíríkì, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí ọbìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kírísítì Jésù Bí ẹ̀yin bá sì jẹ́ ti Kírísítì, ǹjẹ́ ẹ̀yin ní irú-ọmọ Ábúráhámù, àti àrólé gẹ́gẹ́ bí ìlérí Ìtara Pọ́ọ̀lù Fún Àwọn Ará Gálátiì Ǹjẹ́ ohun tí mo ń wí ni pé, níwọ̀n ìgbà tí àrólé náà bá wà ní èwe, kò yàtọ̀ nínú ohunkóhun sí ẹrú bí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa ohun gbogbo Ṣùgbọ́n ó wà lábẹ́ olùtọ́jú àti ìríjú títí àkókò tí baba ti yàn tẹ́lẹ̀ Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwa, nígbà tí àwa wà ní èwe, àwa wà nínú ìdè lábẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin Láti ra àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin padà, kí àwa lè gba ìsọdọmọ, Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, Ábà, Baba Nítorí náà ìwọ kì í ṣe ẹrú, bí kò ṣe ọmọ àti bí ìwọ bá ń ṣe ọmọ, ǹjẹ́ ìwọ di àrólé Ọlọ́run nípaṣẹ̀ Kírísítì Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin kò tí i mọ Ọlọ́run, ẹ̀yin ti sìnrú fún àwọn tí kì í ṣe Ọlọ́run nípa ẹ̀dá Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà tí ẹ̀yin ti mọ Ọlọ́run tan tàbí kí a ṣá kúkú wí pé ẹ di mímọ́ fún Ọlọ́run, è é ha ti rí tí ẹ tún fi yípadà sí aláìlera àti alágbe ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí ẹ̀yin tún fẹ́ padà wá sìnrú Ẹ̀yin ń kíyèsí ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún Ẹ̀rù yin ń bà mí, kí o má bà ṣe pé lásán ni mo ṣe làálàá lórí yín Ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dà bí èmi nítorí èmi dà bí ẹ̀yin èyin kò ṣe mí ní ibi kan Ẹ̀yin mọ̀ pé nínú àìlera ni mo wàásù ìhìnrere fún yín ní àkọ́kọ́ Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí áńgẹ́lì Ọlọ́run, àní bí Kírísítì Jésù Ǹjẹ́ ayọ̀ yín ìgbà náà há dà Nítorí mo gba ẹ̀rí yín pé, ìbá ṣe é ṣe, ẹ̀ ò bá yọ ojú yín jáde, ẹ̀ bá sì fi wọ́n fún mi Ǹjẹ́ mo há di ọ̀ta yín nítorí mo sọ òtítọ́ fún yín bí Wọ́n ń fi ìtara wá yin, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún rere wọ́n ń fẹ́ já yin kúrò, kí ẹ̀yin lè máa wá wọn Ṣùgbọ́n ó dára láti máa fi ìtara wáni fún rere nígbà gbogbo, kì í sìí ṣe nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nìkan Ẹ̀yin ọmọ mi kékèké, ẹ̀yin tí mo tún ń rọbí títí a ó fi ṣe ẹ̀dá Kírísítì nínú yín Ìbá wù mí láti wà lọ́dọ̀ yín nísinsìnyìí, kí èmi sì yí ohùn mi padà nítorí pé mo dààmú nítorí yín Ẹ wí fún mi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ wà lábẹ́ òfin, ẹ ko ha gbọ́ òfin Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Ábúráhámù ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira-obìnrin ni a bí nípa ìlérí Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní méjẹ̀mú méjèèjì ọ̀kan láti orí òkè Sínáì wá, tí a bí lóko-ẹrú, tí í ṣe Hágárì Nítorí Hágárì yìí ni òkè Sínáì Árábíà, tí ó sì dúró fún Jerúsálémù tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko-ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ Ṣùgbọ́n Jerúsálémù ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Má a yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn tí kò bímọ, bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀ yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Ísáákì Ṣùgbọ́n bí èyí tí a bí nípa ti ara ti ṣe inúnibíni nígbà náà sí èyí tí a bí nípa ti Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni nísinsìnyìí Ṣùgbọ́n ìwé-mímọ́ ha ti wí, Lé ẹrú-bìnrin náà jáde àti ọmọ rẹ̀ nítorí ọmọ ẹrú-bìnrin kì yóò bá ọmọ òmìnira-obìnrin jogún pọ̀ Nítorí náà, ará, àwa kì í ṣe ọmọ ẹrú-bìnrin bí kò ṣe ti òmìnira obìnrin Òmìnira Nínú Jésù Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin nínú òmìnira náà èyí tí Kírísítì fi sọ wá di òmìnira, kí ẹ má sì ṣe tún fi ọrùn bọ̀ àjàgà ẹrú mọ́ Kíyèsí i, èmi Pọ́ọ̀lù ni ó wí fún yín pé, bí a bá kọ yín nílà, Kírísítì kì yóò lérè fún yín ní ohunkóhun Mo sì tún sọ fún olúkúlùkù ènìyàn tí a kọ ní ilà pé, ó di ajigbésè láti pa gbogbo òfin mọ́ A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kírísítì, ẹ̀yin tí ń fẹ́ kí a dá yín láre nípa òfin pé ẹ ti ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́ Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo Nítorí nínú Kírísítì Jésù ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́ Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ran sí òtítọ́ Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìyẹ̀fun wú Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí yín nínú Olúwa pé, ẹ̀yin kì yóò ní èrò ohun mìíràn ṣùgbọ́n ẹni tí ń yọ yín lẹ́nu yóò ru ìdájọ́ tirẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́ Ṣùgbọ́n, ará, bí èmi bá ń wàásù ìkọlà síbẹ̀, kín ni ìdí tí a fi ń ṣe inúnibíni sí mi síbẹ̀ Ǹjẹ́ ìkọsẹ̀ àgbélébùú ti kúrò Èmi ìbá fẹ́ kí àwọn tí ń yọ yín lẹ́nu tilẹ̀ gé ẹ̀yà-ara wọn kan kúrò Nítorí a ti pè yín sí òmìnira, ará kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín bí àǹfààní sípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìfẹ́ sin ọmọnìkejjì yín Nítorí pé a kó gbogbo òfin já nínú èyí pé, Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń bu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín run, ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe pa ara yín run Ǹjẹ́ mo ní, Ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ́ ti ara ṣẹ Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn kí ẹ má baà lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́ Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mi samọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tíí ṣe wọ̀nyí panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà, Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórira, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtara-ẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́-òdí Àrankan, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde-òru, àti irú ìwọ̀nyí àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run Ṣùgbọ́n èèso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwàpẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, Ìwà-tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí, Àwọn tí í ṣe ti Kírísítì Jésù ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ Bí àwa bá wà láàyè sípa ti Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a sì máa rìn nípa ti Ẹ̀mí Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa ṣògo-asán, kí a má mú ọmọnìkejì wa bínú, kí a má ṣe ìlara ọmọnìkejì wa Síse Dáradára Sí Gbogbo Ènìyàn Ará, bí a tilẹ̀ mú ẹnìkan nínú ẹ̀sẹ̀ kan, kí ẹ̀yin tí í ṣe ti Ẹ̀mí mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò nínú ẹ̀mí ìwà tútù kí ìwọ tìkárarẹ̀ máa kíyèsára, kí a má baà dán ìwọ náà wò pẹ̀lú Ẹ máa ru ẹrù ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì fi bẹ́ẹ̀ mú òfin Kírísítì ṣẹ Nítorí bí ènìyàn kan bá ń ro ara rẹ̀ sí ẹnìkan, nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà, ohun ìmú-ṣogo rẹ̀ yóò jẹ́ nínú ti ara rẹ̀ nìkan, kì yóò sì jẹ nínú ti ọmọnìkejì rẹ̀ Nítorí pé olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ara rẹ̀ Ṣùgbọ́n kí ẹni tí a ń kọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà máa pèsè ohun rere gbogbo fún ẹni tí ń kọ́ni Kí a má ṣe tàn yín jẹ a kò lè gan Ọlọ́run nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òhun ni yóò sì ká Nítorí ẹni tí ó bá ń fúnrúngbìn sípa ti ara yóò ká ìdíbàjẹ́ ti ara ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúngbìn sípa ti ẹ̀mí yóò ti inú ẹ̀mí ká ìyè àìnípẹ̀kun Ẹ má sì jẹ́ kí àárẹ̀ ọkàn mú wa ní ṣíṣe rere, nítorí tí a ó kórè nígbà tí àkókò bá dé, bí a kò bá ṣe àárẹ̀ Ǹjẹ́ bí a ti ń rí àkókò, ẹ jẹ́ kí a máa ṣoore fún gbogbo ènìyàn, àti pàápàá fún àwọn tí í ṣe ará ilé ìgbàgbọ́ Ẹ wo bí mo ti fi ọwọ́ ara mi kọ̀wé gàdàgbà-gàdàgbà sí yín Iye àwọn tí ń fẹ́ ṣe àṣehàn ni ara wọn ń rọ yín láti kọlà kìkì nítorí pé kí a má ba à ṣe inúnibíni sí wọn nítorí àgbélébùú Kírísítì Nítorí àwọn tí a kọ nílà pàápàá kò pa òfin mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ mú yin kọlà, kí wọn lè máa ṣògo nínú ara yín Ṣùgbọ́n kí a má ṣe rí i pé èmi ń ṣògo, bí kò ṣe nínú àgbélébùú Jésù Kírísítì Olúwa wa, nípaṣẹ̀ ẹni tí a ti kan ayé mọ́ àgbélébùú fún mi, àti èmi fún ayé Nítorí pé nínú Kírísítì Jésù ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà, bí kò ṣe ẹ̀dá tuntun Kí àlàáfíà àti àánú wà lórí gbogbo àwọn tí ń rìn ní ìlànà yìí, àti lórí Ísírẹ́lì Ọlọ́run Láti isinsínyìí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu mọ́ nítorí èmi ń ru àpá Jésù Olúwa kiri ní ara mi Ará, oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín Àmín Ìbẹ̀rẹ̀ Dídá Ayé Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rá bàbà lójú omi gbogbo Ọlọ́run sì wí pé, Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní Ọ̀sán àti òkùnkùn ní Òru Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní Ọlọ́run sì wí pé Jẹ́ kí òfuurufú kí ó wà ní àárin àwọn omi láti pààlà sí àárin àwọn omi Ọlọ́run sì dá òfuurufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfuurufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀ Ó sì rí bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run sì pe òfúurufú ní Ọ̀run, àsálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì Ọlọ́run sì wí pé, Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojúkan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn Ó sì rí bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní Ilẹ̀ àti àpapọ̀ omi ní Òkun Ọlórun sì rí i wí pé ó dára Ọlọ́run sì wí pé, Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn ewéko ti yóò máa mú èṣo wá àti igi tí yóò máa so èṣo ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú Ó sì rí bẹ́ẹ̀ Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn ewéko tí ó ń so èṣo ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èṣo, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀ Ọlọ́run sì ri pé ó dára Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹta Ọlọ́run sì wí pé Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, làti pààlà sí àárin ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún, Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run, láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀ Ó sì rí bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńlá-ńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ si orí ilẹ̀, láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárin ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn Ọlọ́run sì rí i pé ó dára Àsálẹ́ àti òwúrọ jẹ́ ọjọ́ kẹrin Ọlọ́run sì wí pé, Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfuurufú Nítorí náà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá alààyè ńlá-ńlá sí inú òkun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti àwọn ohun tí ń rìn ní onírúurú tiwọn, àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ ní onírúurú tiwọn Ọlọ́run sì rí i pé ó dára Ọlọ́run súre fún wọn, ó sì wí pé, Ẹ máa bí sí i, ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ kún inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i ní orí ilẹ̀ Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kárùn-ún Ọlọ́run sì wí pé, Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀ Ó sì rí bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀ Ọlọ́run sì rí i pé ó dára Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jọba lórí ẹja òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ohun ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀ Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a akọ àti abo ni ó dá wọn Ọlọ́run sì súre fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ ṣe ìkápá ayé Ẹ ṣe àkóso àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó ń rìn ní orí ilẹ̀ Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, Mo fi gbogbo ọgbìn tí ń so èso fún un yín bí oúnjẹ àti àwọn igi eléso pẹ̀lú Gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín Àti fún àwọn ẹranko inú igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ohun afàyàfà gbogbo ohun tó ní èémí ìyè nínú ni mo fi ewéko fún bí oúnjẹ Ó sì rí bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run sì rí àwọn ohun gbogbo tí ó dá, ó dára gidigidi Àsálẹ́ àti òwúrọ̀, ó jẹ́ ọjọ́ kẹfà Ìran àwọn ọmọ Nóà Èyí ni ìran àwọn ọmọ Nóà Ṣémù, Ámù àti Jáfétì, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi Àwọn ọmọ Jáfétì ni Gómérì, Mágógì, Mádáì, Jáfánì, Túbálì, Méṣékì àti Tírásì Àwọn ọmọ Gómérì ni Áṣíkénásì, Rífátì àti Tógárímà Àwọn ọmọ Jáfánì ni Élíṣà, Tásísì, Kítímù, àti Ródánímù Àwọn ọmọ Ámù ni Kúsì, Mísíráímù, Fútì àti Kénánì Àwọn ọmọ Kúsì ni Ṣébà, Háfílà, Ṣábátà, Rámà, àti Ṣábítékà Àwọn ọmọ Rámà ni Ṣébà àti Dédánì Kúsì sì bí Nímúrọ́dù, èyí tí ó di alágbára àti jagunjagun ní ayé Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, Bí Nímúrọ́dù-ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Bábílónì, Érékì, Ákádì, Kálínéhì, gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣínárì Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí dé Áṣíríà, níbi tí ó ti tẹ ìlú Nínéfè, Réhóbótì àti Kálà, àti Résínì, tí ó wà ní àárin Nínéfè àti Kálà, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí Mísíráímù ni baba ńlá àwọn ará Lúdì, Ánámì, Léhábì, Náfítúhímù Pátírúsímù, Kásílúhímù àti Káfítórímù Kénánì ni baba àwọn ará Sídónì , àti àwọn ara Hítì Àwọn ará Jébúsì, Ámórì, Gágásì Hífì, Áríkì, Sínì, Áfádì, Ṣémárì àti Hámátì Nígbà tí ó ṣe, àwọn ẹ̀yà Kénánì tàn kálẹ̀ Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kénánì sì dé Ṣídónì, lọ sí Gérárì títí dé Gásà, lọ sí Sódómù, Gòmórà, Ádímà àti Ṣébóìmù, títí dé Láṣà Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ámù, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn A bí àwọn ọmọ fún Ṣémù tí Jáfétì jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin Ṣémù sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Ébérì Àwọn ọmọ Ṣémù ni Élámù, Ásọ̀, Áfákísádì, Lúdì àti Árámù Àwọn ọmọ Árámù ni Úsì, Úlì, Gétérì àti Méṣékì Áfákísádì ni baba Ṣélà, Ṣélà yìí sì ni ó bí Ébérì Ébérì sì bí ọmọ méjì ọ̀kan sì ń jẹ́ Pélégì, nítorí ní ìgbà ayé rẹ̀ ni ilẹ̀ ayé pín sí oríṣìíríṣìí ẹ̀yà àti èdè Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jókítanì Jókítanì sì bí Álímádádì, Ṣéléfì, Hásámáfétì àti Jérà Hádórámù, Húsálì, Díbílà Óbálì, Ábímáélì, Ṣébà Ófírì, Áfílà àti Jóbábù Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jókítanì Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Méṣà títí dé Ṣéfárì, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà oòrùn Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣémù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀ èdè wọn Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Nóà gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, ní orílẹ̀ èdè wọn Ní ipaṣẹ̀ wọn ni àwọn ènìyàn ti tàn ká ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìkún omi Ilé-ìṣọ́ Bábílónì Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀ṣíwájú lọ sí ìhà ìlà oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Sínárì , wọ́n sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀ Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sun wọ́n jiná Bíríkì ni wọn ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun Nígbà náà ni wọ́n wí pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé-ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí á baà lè ní orúkọ kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé Ṣùgbọ́n, Olúwa sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú àti ilé-ìṣọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń kọ́ Olúwa wí pé, Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbérò tí wọn kò ní le ṣeyọrí Ẹ̀ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má baà yé ara wọn mọ́ Ọlọ́run sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó Ìdí èyí ni a fi pè é ní Bábílónì nítorí ní ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti da èdè gbogbo ayé rú, tí ó sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé Wọ̀nyí ni ìran Ṣémù Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣémù pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Áfákísádì Lẹ́yìn tí ó bí Áfákísádì, ó tún wà láàyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún , ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn Nígbà tí Áfákísádì pé ọdún marùndínlógójì ni ó bí Ṣélà Ó sì wà láàyè fún ọdún mẹ́talénírínwó lẹ́yìn tí ó bí Ṣélà, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn Nígbà tí Ṣélà pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Ébérì Ó sì wà láàyè fún ọdún mẹ́talénírinwó lẹ́yìn tí ó bí Ébérì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn Ébérì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n , ó sì bí Pélégì Ébérì sì wà láàyè fún irínwó-ó-lé-ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn tí ó bí Pélégì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn Nígbà tí Pélégì pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Réù Ó sì tún wà láàyè fún igba-ó-lé-mẹ́sàn án ọdún lẹ́yìn tí ó bí Réù, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn Nígbà tí Réù pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó bí Ṣérúgì Ó tún wà láàyè lẹ́yìn tí ó bí Ṣérúgì fún igba-ó-lé-méje ọdún , ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn Nígbà tí Ṣérúgì pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Náhórì Ó sì wà láàyè fún igba ọdún lẹ́yìn tí ó bí Náhórì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn Nígbà tí Náhórì pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n , ó bí Tẹ́rà Ó sì wà láàyè fún ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́fà lẹ́yìn ìbí Tẹ́rà, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn Lẹ́yìn tí Tẹ́rà pé ọmọ àádọ́rin ọdún ó bí Ábúrámù, Náhórì àti Háránì Wọ̀nyí ni ìran Tẹ́rà Tẹ́rà ni baba Ábúrámù, Náhórì àti Áránì, Áránì sì bí Lọ́tì Áránì sì kú ṣáájú Tẹ́rà baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Úrì ti ilẹ̀ Kálídéà Ábúrámù àti Náhórì sì gbéyàwó Orúkọ aya Ábúrámù ni Sáráì, nígbà tí aya Náhórì ń jẹ́ Mílíkà, tí ṣe ọmọ Áránì Áránì ni ó bí Mílíkà àti Ísíkà Sáráì sì yàgàn, kò sì bímọ Tẹ́rà sì mú ọmọ rẹ̀ Ábúrámù àti Lọ́tì ọmọ Áránì, ọmọ-ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sáráì tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀ Ábúrámù pẹ̀lú, gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Úrì ti Kálídéà láti lọ sí ilẹ̀ Kénánì Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Áránì wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀ Nígbà tí Tẹ́rà pé ọmọ igba ó lé márùn-ún ọdún ni ó kú nì Áránì Ìpè Ábúrámù Olúwa sì wí fún Ábúrámù, Jáde kúrò ní ile rẹ àti lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ àti kúrò ní ìdílé baba rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi ó fi hàn ọ́ Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá Èmi yóò sì bùkún fún ọ Èmi yóò sọ orúkọ rẹ di ńlá, ìbùkún ni ìwọ yóò sì jásí Àwọn tí ó súre fún ọ ni Èmi yóò súre fún, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré Nípaṣẹ̀ rẹ ni a ó sì bùkún gbogbo ènìyàn ayé Bẹ́ẹ̀ ni Ábúrámù lọ bí Olúwa ti sọ fún un Lọ́tì náà sì bá a lọ Ábúrámù jẹ́ ẹni àrùndínlọ́gọ́rin ọdún nígbà tí ó jáde kúrò ní Háránì Ábúrámù sì mú Ṣáráì aya rẹ̀, àti Lọ́tì ọmọ arákùnrin rẹ̀ gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti kó jọ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ní Háránì Wọ́n sì jáde lọ sí ilẹ̀ Kénánì Wọ́n sì gúnlẹ̀ ṣíbẹ̀ Ábúrámù sì rìn la ilẹ̀ náà já títí dé ibi igi ńlá kan tí à ń pè ni Móórè ní Ṣékémù Àwọn ará Kénánì sì wà ní ilẹ̀ náà Olúwa sì farahan Ábúrámù, ó sì wí fún un pé, Ìran rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún Ábúrámù tẹ́ pẹpẹ kan ṣíbẹ̀ fún Olúwa tí ó fara hàn-án Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà oòrùn Bẹ́tẹ́lì, ó sì pàgọ́ rẹ̀ ṣíbẹ̀ Bẹ́tẹ́lì wà ní ìwọ̀ oòrùn, Háì wà ní ìlà oòrùn Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa , ó sì ké pe orúkọ Olúwa Nígbà náà ni Ábúrámù tẹ̀ṣíwájú sí ìhà gúsù ni Gúúsù Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, Ábúrámù sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì láti ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, nítorí ìyàn náà mú gidigidi Bí ó ti ku díẹ̀ kí ó wọ Éjíbítì, ó wí fún Ṣáráì, aya rẹ̀ pé, Mo mọ̀ pé arẹwà obìnrin ni ìwọ, nígbà tí àwọn ara Éjíbítì bá rí ọ, wọn yóò wí pé, Aya rẹ̀ nìyí Wọn yóò si pa mí, ṣùgbọ́n wọn yóò dá ọ sí Nítorí náà, sọ pé, arábìnrin mi ni ìwọ, wọn yóò sì ṣe mí dáradára, a ó sì dá ẹ̀mí mi sí nítorí tìrẹ Nígbà tí Ábúrámù dé Éjíbítì, àwọn ará Éjíbítì ri i pé aya rẹ̀ rẹwà gidigidi Nígbà tí àwọn ìjòyè Fáráò sì rí i, wọ́n ròyìn rẹ̀ níwájú u Fáráò, Wọ́n sì mú un lọ sí ààfin, Ó sì kẹ́ Ábúrámù dáradára nítorí Ṣáráì, Ábúrámù sì ní àgùntàn àti màlúù, akọ àti abo, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, pẹ̀lú u ràkunmí Olúwa sì rán àjàkálẹ̀-àrùn búburú sí Fáráò àti ilé rẹ̀, nítorí Sáráì aya Ábúrámù Nítorí náà Fáráò ránṣẹ́ pe Ábúrámù, ó sì wí fun pé, Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí Kí n ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé aya rẹ ní í ṣe Èéṣe tí o fi wí pé, Arábìnrin mi ni, tí èmi sì fi fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí aya Nítorí náà nísinsin yìí, aya rẹ náà nìyí, mú un kí sì o máa lọ Nígbà náà ni Fáráò pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa Ábúrámù, wọ́n sì lé e jáde ti òun ti aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní Ìpínyà Ábúrámù àti Lọ́tì Ábúrámù sì gòkè láti Éjíbítì lọ sí Nẹ́gẹ́fù ní ìhà gúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọ́tì pẹ̀lú Ábúrámù sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi, ní ẹran-ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà Láti Gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Bẹ́tẹ́lì, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú ri lágbedeméjì Bẹ́tẹ́lì àti Áì Ní ibi tí ó ti tẹ́ pẹpẹ sí rí tẹ́lẹ̀ Ábúrámù sì ké pe orúkọ Olúwa Lọ́tì, tí ó ń bá Ábúrámù kiri pẹ̀lú ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àwọn àgọ́ tirẹ̀ Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun-ìní wọn pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, débi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀ Èdè àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn darandaran Ábúrámù àti ti Lọ́tì Àwọn ará a Kénánì àti àwọn ará Pérísítì sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà Ábúrámù sì wí fún Lọ́tì pé, Mo fẹ́ kí a fòpin sí èdè àìyedè tí ó wà láàrin èmi àti ìwọ àti láàrin àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí ni wá Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ Jẹ́ kí a pínyà Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwo lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún Lọ́tì sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa , bí ilẹ̀ Éjíbítì, ní ọ̀nà Ṣóárì Nítorí náà Lọ́tì yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà oòrùn Òun àti Ábúrámù sì pínyà Ábúrámù ń gbé ni ilẹ̀ Kénánì, Lọ́tì sì jókòó ní ìlú agbègbè àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Ṣódómù Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ṣódómù jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́sẹ̀ gidigidi ni ìwájú Olúwa Olúwa sì wí fún Ábúrámù lẹ́yìn ìpínyà òun àti Lọ́tí pé, Gbé ojú rẹ sókè níṣinṣin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúsù, sí ìlà oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀ Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ní èmi ó fi fún ọ àti irú ọmọ rẹ láéláé Èmi yóò mú kí irú ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀ Àyàfi bí ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò tó lè ka irú ọmọ rẹ Dìde, rìn òòró àti ìbú ilẹ̀ náà já, nítorí ìwọ ni Èmi yóò fi fún Nígbà náà ni Ábúrámù kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá láti máa gbé lẹ́bá a igbó Mámúrè ní Hébírónì níbi tí ó tẹ́ pẹpẹ kan sí fún Olúwa Ábúrámù gba Lọ́tì là Ní àsìkò yìí ni Ámúráfélì ọba Ṣínárì, Áríókù ọba Élásárì, Kédóláómérì ọba Élámù àti Tídálì ọba Góímù jáde lọ láti bá Bérà ọba Ṣódómù, Bírísà ọba Gòmórà, Ṣínábù ọba Ádímà, Ṣémébérì ọba Ṣébóímù àti ọba Bélà jagun Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí àfonífojì Ṣídímù Fún ọdún méjìlá gbáko ni wọ́n ti ń sin Kédóláómérì bí ẹrú Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún kẹtàlá wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kédóláómérì àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n sígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ara Ráfáímù ní Aṣilerótì-Kánáímù, àwọn ará Ṣúsítù ni Ámù, àwọn ará Émímù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriátaímù, àti àwọn ará Hórì ní orí-òkè wọ̀nnì Ṣéírì, títí ó fi dé Eli-Páránì ní etí ijù Wọ́n sì tún yípadà lọ sí Ẹn-Mísífátì , wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ àwọn Ámálékì, àti àwọn ará Ámórì tí ó tẹ̀dó sí Haṣaṣoní Támárì pẹ̀lú Nígbà náà ni ọba Ṣódómù, ọba Gòmórà, ọba Ádímà, ọba Ṣébóímù àti ọba Bélà , kó àwọn ọmọ ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó-ogun wọn sí àfonífojì Ṣídímù, láti kojú ìjà sí Kedolaómérì ọba Élámù, Tídà ọba Góímù, Ámúráfélì ọba Ṣínárì àti Áríókì ọba Élásà Àfonífojì Ṣídímù sì kún fún kòtò ọ̀dà-ilẹ̀, nígbà tí ọba Ṣódómù àti ọba Gòmórà sì ṣá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà subú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Ṣódómù àti Gòmórà àti oúnjẹ wọn wọ́n sì lọ Wọ́n sì mú Lọ́tì ọmọ arákùnrin Ábúrámù tí ń gbé ní Ṣódómù àti gbogbo ohun-ìní rẹ̀ Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Ábúrámù, ará Ébérù Ábúrámù sá ti tẹ̀dó sí igbó igi Óákù tí ó jẹ́ ti Mámúrè ará Ámórì, arákùnrin Ésíkólì àti Ánérì àwọn ẹni tí ó ń bá Ábúrámù ní àṣepọ̀ Nígbà tí Ábúrámù gbọ́ wí pé, a di Lọ́tì ní ìgbékùn, o kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ́ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó-lé-lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì ènìyàn , ó sì lépa wọn títí dé Dánì Ní ọ̀gànjọ́ òru, Ábúrámù pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí méjì, ó sì kọlù wọ́n, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn títí dé Oba, ní àríwá Dámásíkù Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọ́tì pẹ̀lú ohun-ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tó kù Nígbà tí Ábúrámù ti ṣẹ́gun Kedolaómérì àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Ṣódómù lọ pàdé e rẹ̀ ní àfonífojì Ṣáfè Mélíkísédékì ọba Ṣálẹ́mù sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá Òun ni àlùfáà Ọlọ́run, ọ̀gá ògo Ó sì súre fún Ábúrámù wí pé, Ìbùkún ni fún Ábúrámù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ọ̀gá ògo tí ó dá ọ̀run òun ayé Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run ọ̀gá ògo jùlọ tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ Ábúrámù sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo Ọba Ṣódómù sì wí fún Ábúrámù pé, Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ Ṣùgbọ́n Ábúrámù dá ọba Ṣódómù lóhùn pé, Mo ti búra fún Olúwa , Ọlọ́run ọ̀gá ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè, pé, èmi kì yóò mú ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ se tèmi, ìbáà kéré bí orí abẹ́rẹ́, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, Mo sọ Ábúrámù di ọlọ́rọ̀ Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Ánérì, Ésíkólì àti Mámúrè Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn Májẹ̀mu Ọlọ́run Pẹ̀lú Ábúrámù Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Ábúrámù wá lójú ìran pé Ábúrámù má ṣe bẹ̀rù, Èmi ni ààbò rẹ, Èmi sì ni èrè ńlá rẹ Ṣùgbọ́n Ábúrámù wí pé, Olúwa , alágbára, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Élíásérì ará Dámásíkù ni yóò sì jogún mi, Ábúrámù sì tún tẹ̀ṣíwájú pé, Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé è mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnrarẹ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ Olúwa sì mú Ábúrámù jáde síta ó sì wí fún un pé, Gbójú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀-bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n Ó sì wí fun un pé, Nítorí náà, báyìí ni irú ọmọ rẹ yóò rí Ábúrámù sì gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sì òdodo fun-un Ó sì tún wí fún un pé, Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Úrì ti Kálídéà láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún Ṣùgbọ́n Ábúrámù wí pé, Olúwa Ọlọ́run, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi Nítorí náà, Olúwa wí fún-un pé, Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́tamẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan Ábúrámù sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjìméjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣugbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Ábúrámù sì ń lé wọn Bí oòrùn ti ń wọ̀, Ábúrámù sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, Mọ èyí dájú pé, àwọn ìran rẹ yóò ṣe àtìpó ní orílẹ̀ èdè tí kì í ṣe ti wọn, a ó kó wọn lẹ́rú, a ó sì jẹ wọ́n ní ìyà fún irínwó ọdún Ṣùgbọ́n èmi yóò dá orílẹ̀ èdè náà tí wọn yóò sìn lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀ Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin Ní ìran kẹ́rin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Ámórì kò ì tí ì kún òṣùwọ̀n Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì sú, ìkòkò iná tí ń sèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrin ẹ̀là a ẹran náà Ní ọjọ́ náà gan-an ni Olúwa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ábúrámù, ó sì wí pé, Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Éjíbítì dé odò ńlá Yúfúrátè ilẹ̀ àwọn ará Kénì, Kádímónì, Ítì, Pérísísì, Réfáímù Ámórì, Kénánì, Gírígásì àti Jébúsì Ṣáráì, aya Ábúrámù kò bímọ fún un, ṣùgbọ́n ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrini ará Éjíbítì kan tí ń jẹ́ Ágárì Nítorí náà, Ṣáráì wí fún Ábúrámù pé, Kíyèsí i Olúwa ti sé mi ní inú, èmi kò sì bímọ, wọlé tọ ọmọ ọ̀dọ̀ mi lọ, bóyá èmi yóò le ti ipaṣẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ Ábúrámù sì gba ohun tí Ṣáráì sọ Lẹ́yín ọdún mẹ́wàá tí Ábúrámù ti ń gbé ni Kénánì ni Ṣáráì mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hágárì, tí í ṣe ará Éjíbítì fún Ábúrámù ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya Ábúrámù sì bá Ágárì lòpọ̀, ó sì lóyún Nígbà tí ó sì ti mọ̀ pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sì ní kẹ́gàn ọ̀gá rẹ̀ Nígbà náà ni Ṣáráì wí fún Ábúrámù pé, Ìwọ ni ó jẹ́ kí ẹ̀gbin yìí máa jẹmí, mo fa ọmọ ọ̀dọ̀ mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó sì rí i pé òun lóyún, mo di ẹni ẹ̀gàn ní ojú rẹ̀ Kí Olúwa kí ó ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àti ìwọ Ábúrámù dáhùn pé, Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i Nígbà náà ni Ṣáráì fi ìyà jẹ ẹ́, ó sì sá lọ Ańgẹ́lì Olúwa sì rí Ágáì ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀na tí ó lọ sí Ṣúrì Ó sì wí pé, Hágárì, ìránṣẹ́ Ṣáráì, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ Ó sì dáhùn pé, Mo ń sá lọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Ṣáráì ni Ańgẹ́lì Olúwa sì wí fún un pé, Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un Ańgẹ́lì náà sì fi kún fún un pé, Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá, ìran rẹ kì yóò sì lóǹkà Ańgẹ́lì náà sì wí fún un pé, Ìwọ ti lóyún ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Íṣímáélì, nítorí tí Olúwa ti rí ìpọ́njú rẹ Òun yóò jẹ́ ẹhànnà ènìyàn yóò máa tako gbogbo ènìyàn, gbogbo ènìyàn yóò sì máa takò ó, kì yóò sì bá awọn arákùnrin rẹ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀ Ó sì fi pe Olúwa tí o bá sọ̀rọ̀ ní, Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi, nítorí tí ó wí pé, Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Róì kànga ẹni alààyè tí ó rí mi Ó wà lágbedeméjì Kédásì àti Bérédì Ágárì sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúrámù, Ábúrámù sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísímáélì Ábúrámù jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndín-láàádọ́rùn-ún nígbà tí Hágárì bí Ísímáélì fún-un Àmì Májẹ̀mu Ní ìgbà tí Ábúrámù di ẹni ọ̀kàndínlọ́gọ́rùnún ọdún, Olúwa farahàn án, ó sì wí pé, Èmi ni Ọlọ́run alágbára, máa rìn níwájú mi, kí o sì jẹ́ aláìlábùkù Èmi yóò sì fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ Èmi yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ gidigidi Ábúrámù sì dojúbolẹ̀, Ọlọ́run sì wí fún un pé Ní ti èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ nìyí Ìwọ yóò di baba orílẹ̀ èdè púpọ̀ A kì yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Ábúrámù mọ́, bí kò ṣe Ábúráhámù, nítorí, mo ti sọ ọ́ di baba orílẹ̀ èdè púpọ̀ Èmi yóò mú ọ bí si lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè ni èmi yóò sì mú ti ara rẹ jáde wá, àwọn ọba pẹ̀lú yóò sì ti inú rẹ jáde Èmi yóò sì gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ láàrin èmi àti ìwọ, ní májẹ̀mú ayérayé àti láàrin irú ọmọ rẹ ní ìran-ìran wọn, láti máa ṣe Ọlọ́run rẹ àti ti irú ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ Gbogbo ilẹ̀ Kénánì níbi tí ìwọ ti ṣe àjèjì ni èmi yóò fi fún ọ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ láéláé, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Ábúráhámù pé, Ìwọ máa pa májẹ̀mú mí mọ́, ìwọ àti irú ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ àti àwọn ìran tí ó ń bọ̀ Èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ, májẹ̀mú tí ẹ gbọdọ̀ pa mọ́ Gbogbo ọkùnrin yín ni a gbọdọ̀ kọ ní ilà Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrin wa Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ̀yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀ Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrin Èmi àti irú ọmọ rẹ Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí fi owó rà, gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé Gbogbo ọmọkùnrin tí kò bá kọ ilà, tí a ko kọ ní ilà abẹ́, ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó da májẹ̀mú mi Ọlọ́run wí fún Ábúráhámù pé, Ní ti Ṣáráì, aya rẹ̀, ìwọ kì yóò pè é ní Ṣáráì bí kò ṣe Ṣárà Èmi yóò bùkún fún-un, Èmi yóò sì fun ọ ní ọmọkùnrin kan nípaṣẹ̀ rẹ̀ Èmi yóò bùkún-un, yóò sì di ìyá àwọn orílẹ̀ èdè, àwọn ọba àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì ti ara rẹ̀ jáde wá Ábúráhámù sì dojúbolẹ̀, ó rẹ́rìn-ín, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, A ó ha bí ọmọ fún ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún Ṣárà tí í ṣe ẹni àádọ́rùn-ún ọdún yóò ha bímọ bí Ábúráhámù sì wí fún Ọlọ́run pé, Ṣá à jẹ́ kí Ísímáélì kí ó wà láàyè lábẹ́ ìbùkún rẹ Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, Mo gbọ́, ṣùgbọ́n Ṣárà aya rẹ̀ yóò bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísáákì, èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní májẹ̀mú ayérayé àti àwọn irú ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ Ṣùgbọ́n ní ti Ísímáélì, mo gbọ́ ohun tí ìwọ wí, èmi yóò bùkún fún-un ní tòótọ́, èmi ó sì mú un bí sí i, yóò sì pọ̀ sí i, òun yóò sì jẹ́ baba fún àwọn ọmọ-ọba méjìlá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú Ísáákì, ẹni tí Ṣárà yóò bí fún ọ ni ìwòyí àmọ́dún Nígbà tí ó ti bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ tán, Ọlọ́run sì gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ Ní ọjọ́ náà gan-an ni Ábúráhámù mú Ísímáélì ọmọ rẹ̀ àti àwọn ẹrú tí a bí ní ilé rẹ̀ àti àwọn tí ó fi owó rà, ó sì kọ wọ́n ní ilà Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kọ gbogbo ọkùnrin tí ń bẹ ní ilé rẹ̀ ní ilà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa Ábúráhámù jẹ́ ẹni ọ̀kàndínlọ́gọ́rùnún ọdún nígbà tí a kọ ọ́ ní ilà Ísímáélì ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹni ọdún mẹ́talá, Ábúráhámù pẹ̀lú rẹ̀ kọ ilà ní ọjọ́ náà gan-an Àti gbogbo ọkùnrin tí ó wà ní ilé Ábúráhámù, ìbá à ṣe èyí tí a bí ní ilé rẹ̀ tàbí èyí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àlejò ni a kọ ní ílà pẹ̀lú rẹ̀ Àwọn àlejò mẹ́ta Olúwa sì farahan Ábúráhámù ní tòsí àwọn igi ńlá Mámúrè, bí ó ti jókòó ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, nígbà tí ọjọ́ kanrí tí oòrùn sì mú Ábúráhámù gbójú sókè, ó sì rí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọn dúró nítòsí rẹ̀ Nígbà tí ó rí wọn, ó sáré láti lọ pàdé wọn, ó sì tẹríba bí ó ti ń kí wọn Ó wí pé, Bí mo bá rí ojú rere yín Olúwa mi, ẹ má ṣe lọ láì yà sọ́dọ̀ ìránṣẹ́ yín Ẹ jẹ́ kí a bu omi díẹ̀ wá kí ẹ̀yin kí ó wẹ ẹṣẹ̀ yín, kí ẹ sì sinmi lábẹ́ igi níhìn-ín Ẹ jẹ́ kí n wá oúnjẹ wá fún-un yín kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ, kí ara sì tù yín, kí ẹ si tẹ̀ṣíwájú ní ọ̀nà yín, nígbà tí ẹ ti yà ní ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ yín Wọn sì wí pé Ó dára Ábúráhámù sì yára tọ Ṣárà aya rẹ̀ lọ nínú àgọ́, ó wí pé, Tètè mú òṣùwọn ìyẹ̀fun dáradára mẹ́ta kí o sì pò ó pọ̀, kí o sì ṣe oúnjẹ Ó sì tún sáré lọ sí ibi agbo ẹran, ó sì mú ọmọ màlúù kan fún ìránṣẹ́ rẹ̀, ìránṣẹ́ náà sì tètè ṣè é Ó sì mú wàrà àti mílíìkì àti màlúù tí ó ti pèsè, ó sì gbé e ṣíwájú wọn Ó sì dúró nítòòsí wọn lábẹ́ igi bí wọn ti ń jẹ ẹ́ Wọn bèèrè pé, Ṣárà aya rẹ ńkọ́ Ó dáhùn pé, Ó wà nínú àgọ́ Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, Ṣárà aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan Sárà sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn wọn Ábúráhámù àti Ṣárà sì ti di arúgbó Ṣárà sì ti kọjá àsìkò ìbímọ Nítorí náà, Ṣárà rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀ bí ó ti ń rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó tán tí olúwa mi pẹ̀lú sì ti gbó jọ̀kújọ̀kú, èmi yóò ha tún lè bímọ Nígbà náà ni Olúwa wí fún Ábúráhámù pé, Kín ló dé tí Ṣárà fi rẹ́rìn-ín tí ó sì wí pé, Èmi yóò ha bímọ nítòótọ́, nígbà tí mo di ẹni ogbó tan Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí ó sòro jù fún Olúwa Èmi ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí àmọ́dún, Ṣárà yóò si bí ọmọkùnrin Ẹ̀rù sì ba Ṣárà, ó sì sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún-un pé, Dájúdájú ìwọ rẹ́rín-ín Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, wọn kọjú sí ọ̀nà Ṣódómù, Ábúráhámù sì sìn wọ́n dé ọ̀nà Nígbà náà ni Olúwa wí pé, Ǹjẹ́ èmi yóò ha pa ohun tí mo fẹ́ ṣe mọ́ fún Ábúráhámù bí Dájúdájú Ábúráhámù yóò sá à di orilẹ̀ èdè ńlá àti alágbára, a ó sì tipaṣẹ̀ rẹ̀ bùkún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé Nítorí tí èmi ti yàn án láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ará ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, láti máa pa ọ̀nà Olúwa mọ nípa ṣíṣe olóòtọ́ àti olódodo kí Olúwa le è mú ìlérí rẹ̀ fún Ábúráhámù ṣẹ Olúwa sì wí pé, igbe Ṣódómù àti Gòmórà pọ̀ púpọ̀ àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jọjọ Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ síbẹ̀ láti ṣe ìwádìí igbe tí ó dé sí etí ìgbọ́ mi nípa wọn, kí èmi sì mọ òtítọ́ tí ó wà níbẹ̀ Àwọn ọkùnrin náà yí padà, wọ́n sì ń lọ sí ìhà Ṣódómù Ṣùgbọ́n Ábúráhámù dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa Nígbà náà ni Ábúráhámù súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olúwa , ó sì wí pé, Ìwọ yóò ha pa ènìyàn rere àti ènìyàn búrurú run papọ̀ bí Bí ó bá ṣe pé Ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, Ìwọ yóò ha run-ún, Ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tó bi Olúwa wí pé, Bí mo bá rí àádọ́ta olódodo ní ìlú Ṣódómù, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tí wọn Ábúráhámù sì tún tẹ̀ṣíwájú pé, Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú sí Olúwa , èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú, bí ó bá ṣe pe olódodo márùn-dín-làádọ́ta ni ó wà nínú ìlú, Ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí Olúwa dáhùn pé, Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùn-dín-láàádọ́ta nínú rẹ̀ Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, Bí ó bá ṣe pé ogójì ni ńkọ́ Olúwa sì tún wí pé, Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo ogójì nínú rẹ̀ Ábúráhámù sì tún bẹ Olúwa pé, Kí Olúwa má ṣe bínú, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ̀rọ̀ Bí ó bá ṣe pé ọgbọ̀n ni rí níbẹ̀ ńkọ́ Olúwa dáhùn pé, Bí mó bá rí ọgbọ̀n, Èmi kì yóò pa ìlú run Ábúráhámù wí pé, Níwọ̀n bí mo ti ní ìgboyà láti bá Olúwa sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀ṣíwájú Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ńkọ́ Olúwa sì dáhùn pé, Èmi kì yóò pa á run nítorí ogún ènìyàn náà Ábúráhámù sì wí pé, Jọ̀wọ́ má ṣe bínú Olúwa Jẹ́ kí ń béèrè lẹ́ẹ̀kan si Bí ó bá ṣe pé ènìyàn mẹ́wàá ni bá tí ó jẹ́ olódodo ńkọ́ Olúwa wí pé, Nítorí ènìyàn mẹ́wàá náà, Èmi kì yóò pa á run Olúwa sì bá tirẹ̀ lọ, nígbà tí ó bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ tan, Ábúráhámù sì padà sílé Ìparun Sódómù àti Gòmórà Ní àsáálẹ́, àwọn ańgẹ́lì méjì sì wá sí ìlú Ṣódómù, Lọ́tì sì jókòó ní ẹnu ibodè ìlú Bí ó sì ti rí wọn, ó sì dide láti pàdé wọn, ó kí wọn, ó sí foríbalẹ̀ fún wọn Ó wí pé, Ẹ̀yin olúwa mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ yà sí ilé ìránṣẹ́ yín kí ẹ sì wẹ ẹsẹ̀ yín, kí n sì gbà yín lálejò, ẹ̀yin ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti máa bá ìrìnàjò yín lọ Wọ́n sì wí pé, Rárá o, àwa yóò dúró ní ìgboro ní òru òní Ṣùgbọ́n Lọ́tì rọ̀ wọ́n gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n gbà láti bá a lọ sì ilé Ó sì ṣe oúnjẹ fún wọn, ó ṣe Búrẹ́dì aláìwú wọ́n sì jẹ ẹ́ Ṣùgbọ́n kí ó tó di pé wọ́n lọ sùn, àwọn ọkùnrin ìlú Ṣódómù tọmọdé tàgbà yí ilé náà ká Wọ́n pe Lọ́tì pé, Àwọn ọkùnrin tí ó wọ̀ sí ilé rẹ lálẹ́ yìí ńkọ́ Mú wọn jáde fún wa, kí a le ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn Lọ́tì sì jáde láti pàdé wọn, ó sì ti ilẹ̀kùn lẹ́yìn rẹ̀ bí ó ti jáde Ó sì wí pé Rárá, ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe se ohun búburú yìí, kíyèsí i, mo ní ọmọbìnrin méjì tí kò mọ ọkùnrin rí, ẹ jẹ́ kí n mú wọn tọ̀ yín wá kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ fẹ́ pẹ̀lú wọn Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ibi kan nítorí wọ́n wá wọ̀ lábẹ́ ààbò ní ilé mi Wọ́n sì wí fún Lọ́tì pé Yàgò lọ́nà fún wa, o jẹ́ àlejò láàrin wa, o wá ń fẹ́ ṣe onídájọ́ ohun tí a ó fi ṣe ọ́ ju ohun tí a ó fi ṣe wọn lọ Wọn rọ́ lu Lọ́tì, wọ́n sì súnmọ ọn láti fọ́ ilẹ̀kùn Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà nawọ́ fa Lọ́tì wọlé, wọ́n sì ti ilẹ̀kùn Wọ́n sì bu ìfọ́jú lu àwọn ọkùnrin tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà ilé náà, àti èwe àti àgbà wọ́n kò sì rí ẹnu ọ̀nà mọ́ Àwọn ọkùnrin náà sì wí fún Lọ́tì pé, Ǹjẹ́ ó ní ẹlòmíràn ní ìlú yìí bí Àna rẹ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí ẹnikẹ̀ni tí ìwọ ní ní ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò ní ibí yìí, nítorí a ó pa ìlú yìí run, nítorí igbe iṣẹ́ búrurú wọn ń dí púpọ̀ níwájú Olúwa , Olúwa sì rán wa láti pa á run Nígbà náà ni Lọ́tì jáde, ó sì wí fún àwọn àna rẹ̀ ọkùnrin tí ó ti bá jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ pé, Ẹ ṣe kánkán, kí ẹ jáde ní ìlú yìí nítorí Olúwa fẹ́ pa ilu yìí run! Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ wọ̀nyí rò pé àwàdà ló ń ṣe Ní àfẹ̀mọ́jú, àwọn ańgẹ́lì náà rọ Lọ́tì pé, Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìnín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn Nígbà tí ó ń jáfara, àwọn ọkùnrin náà nawọ́ mú un lọ́wọ́, wọ́n sì nawọ́ mú aya rẹ̀ náà lọ́wọ́ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì mú wọn jáde sẹ́yìn odi ìlú, nítorí Olúwa sàánú fún wọn Ní kété tí wọ́n mú wọn jáde tán, ọ̀kan nínú àwọn Ańgẹ́lì náà wí fún wọn pé, Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí ti yín, ẹ má ṣe wẹ̀yìn, orí òkè ni kí ẹ sá lọ, ẹ má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣègbé! Ṣùgbọ́n Lọ́tì wí fún wọn pé, Rárá, ẹ̀yin Olúwa mi, ẹ jọ̀wọ́! Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ti rí oju rere rẹ, tí o sì ti fi àánú rẹ hàn nípa gbígba ẹ̀mí mi là, Èmi kò le è ṣá lọ sórí òkè, kí búrurú yìí má ba à lé mi bá, kí n sì kú Wò ó, ìlú kékeré kan nìyí ní tòòsí láti ṣá sí jẹ́ kí n ṣá lọ ṣíbẹ̀, ìlú kékeré ha kọ́ , Ẹ̀mí mi yóò sì yè Ó sì wí fún un pé, Ó dára, mo gba ẹ̀bẹ̀ rẹ Èmi kì yóò run ìlú náà tí ìwọ sọ̀rọ̀ rẹ̀ Tètè! Sá lọ ṣíbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀, Nígbà tí Lọ́tì yóò fi dé ìlú náà oòrùn ti yọ Nígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti Ṣúlúfúrù ṣórí Ṣódómù àti Gòmórà-láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńláńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀ Ṣùgbọ́n aya Lọ́tì bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di òpó iyọ̀ Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Ábúráhámù sì dìde ó sì padà lọ sí ibi tí ó gbé dúró níwájú Olúwa Ó sì wo ìhà Sódómù àti Gòmórà àti àwọn ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, ó sì rí èéfín tí ń ti ibẹ̀ jáde bí èéfín iná ìléru Ọlọ́run sì rántí Ábúráhámù, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọ́tì jáde kúrò láàrin ìparun náà, tí ó kọ lu ìlú tí Lọ́tì ti gbé Lọ́tì àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì sì kúrò ní Sóárì, wọ́n sì ń lọ gbé ní orí òkè ní inú ihò-àpáta, nítorí ó bẹ̀rù láti gbé ní ìlú Sóárì Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n sọ fún àbúrò rẹ̀ pé, Baba wa ti dàgbà, kò sì sí ọkùnrin kankan ní agbégbé yìí tí ì bá bá wa lò pọ̀, bí ìṣe gbogbo ayé Wá, jẹ́ kí a mú bàbá wa mu ọtí yó, kí ó ba à le bá wa lò pọ̀, kí àwa kí ó lè bí ọmọ, kí ìran wa má ba à parẹ́ Ní òru ọjọ́ náà, wọ́n rọ baba wọn ní ọtí yó Èyí ẹ̀gbọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a lò pọ̀, baba wọn kò mọ̀ ìgbà tí ó sùn ti òun àti ìgbà tí ó dìdè Ní ọjọ́ kejì èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò rẹ̀ pé, Ní àná mo sùn ti bàbá mi Jẹ́ kí a tún wọlé tọ̀ ọ́, kí a lè ní irú ọmọ láti ọ̀dọ̀ baba wa Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fún baba wọn ní ọtí mu yó ni alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àbúrò náà sì wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a lò pọ̀, kò sì tún mọ ìgbà tí ó wọlé ṣùn ti òun tàbí ìgbà tí ó dìde Àwọn ọmọbìnrin Lọ́tì méjèèjì sì lóyún fún baba wọn Èyí ẹ̀gbọ́n sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Móábù Òun ni baba ńlá àwọn ará Móábù lónìí Èyí àbúrò náà sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-Ámì Òun ni baba ńlá àwọn ará Ámónì lónìí Ádámù àti Éfà Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀ Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ń ṣe, ó sì sinmi ní ọjọ́ kéje Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ kéje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run dá ayé àti àwọn ọ̀run, kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí Olúwa Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀ Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀ Olúwa Ọlọ́run sì mọ ènìyàn láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀, ó si mí èémí sí ihò imú rẹ̀, èémí ìyè, ènìyàn sì di ẹ̀dá alààyè Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Édẹ́nì ní ìhà ìlà oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀ àwọn igi tí ó dùn-ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ Ní àárin ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà Odò kan sì ń ti Édẹ́nì sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin Orúkọ èkínní ni Písónì òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Háfílà ká, níbi tí wúrà gbé wà Orúkọ odò kejì ni Gíhónì òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kúsì ká Orúkọ odò kẹta ni Tígírísì òun ni ó sàn ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Áṣúrì Odò kẹ́rin ni Yúfúrátè Olúwa Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Édẹ́nì láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀ Olúwa Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, ìwọ́ lè jẹ lára èyíkéyìí èṣo àwọn igi inú ọgbà ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èṣo igi ìmọ̀ rere àti èṣo igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kú Olúwa Ọlọ́run wí pé, Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀, Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́ Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ Ṣùgbọ́n fún Ádámù ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran ara bò ó padà Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá Ọkùnrin náà sì wí pé, Èyí ni egungun láti inú egungun mi àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi obìnrin ni a ó máa pè é nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòòhò, ojú kò sì tì wọ́n Ábúráhámù àti Ábímélékì Ábúráhámù sì kó kúrò níbẹ̀ lọ sí ìhà gúsù ó sì ń gbé ní agbede-méjì Kádésì àti Ṣúrì ó sì gbé ní ìlú Gérárì fún ìgbà díẹ̀ Ábúráhámù sì sọ ní ti Ṣárà aya rẹ̀ níbẹ̀ pé, Arábìnrin mi ni Ábímélékì ọba Gérárì sì ránṣẹ́ mú Ṣárà wá sí ààfin rẹ̀ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tọ Ábímélékì wá ní ojú àlá lọ́jọ́ kan, ó sì wí fún un pé, Kíyèsi, kò sí ohun tí o fi sàn ju òkú lọ, nítorí obìnrin tí ìwọ mú sọ́dọ̀, aya aláya ni Ṣùgbọ́n Ábímélékì kò tí ì bá obìnrin náà lò pọ̀, nítorí náà ó wí pé, Olúwa ìwọ yóò run orílẹ̀ èdè aláìlẹ́bi bí Ǹjẹ́ òun kò sọ fún mi pé, Arábìnrin mi ni, obìnrin náà pẹ̀lú sì sọ pé, arákùnrin mí ni Ní òtítọ́ pẹ̀lú ọ̀kàn mímọ́ àti ọwọ́ mímọ́, ni mo ṣe èyí Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un nínú àlá náà pé, Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé pẹ̀lú òtítọ́ inú ni ìwọ ṣe èyí, èyí ni mo fi pa ọ́ mọ́ tí ń kò jẹ́ kí o dẹ́ṣẹ̀ sí mi Ìdí nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà Níṣinyìí, dá aya ọkùnrin náà padà, nítorí pé wòlíì ni, yóò sì gbàdúrà fún ọ, ìwọ yóò sì yè Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá dá a padà, mọ̀ dájú pé ìwọ àti gbogbo ẹni tíí ṣe tìrẹ yóò kú Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, Ábímélékì pe gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ Nígbà tí ó sì ṣọ gbogbo ohun tí ó sẹlẹ̀ fún wọn, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi Nígbà náà ni Ábímélékì pe Ábúráhámù ó sì wí fún un pé, Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí Ẹ̀sẹ̀ wo ni mo sẹ̀ ọ́ tí ìwọ fi mú ìdálẹ́bi ńlá wá sí orí èmi àti ìjọba mi Kò yẹ kí ìwọ hu irú ìwà yìí sí mi Ábímélékì sì bi Ábúráhámù pé, Kín ló dé tí ìwọ fi ṣe èyí Ábúráhámù sì dáhùn pé, Mo ṣe èyí nítorí mo rò nínú ara mi pé, ẹ̀yin tí ẹ wà níhìn-ín, ẹ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, pé, ẹ sì le pa mí nítorí aya mi Yàtọ̀ fún ìyẹn, òtítọ́ ni pé arábìnrin mi ni Ọmọ baba kan ni wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a kì í ṣe ọmọ ìyá kan Mo sì fẹ́ ẹ ní aya Nígbà tí Ọlọ́run sì mú mi rìn kiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, Èyí ni ọ̀nà tí ó lè gbà fi hàn pé ó fẹ́ràn mi Gbogbo ibi tí a bá dé máa sọ pé, Arákùnrin rẹ ni mí    Nígbà náà ni Ábímélékì mú àgùntàn àti màlúù wá, àti ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ó sì kó wọn fún Ábúráhámù, ó sì dá Sárà aya rẹ̀ padà fún un Ábímélékì sì tún wí fún un pé, Gbogbo ilé mí nìyí níwájú rẹ, máa gbé ní ibikíbi tí o fẹ́ níbẹ̀ Ábímélékì sì wí fún Ṣárà pé, Mo fi ẹgbẹ̀rún owó ẹyọ fàdákà fún arákùnrin rẹ Éyí ni owó ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ níwájú gbogbo ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ àti pé, a dá ọ láre pátapáta Nígbà náà, Ábúráhámù gbàdúrà sí Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wo Ábímélékì àti aya rẹ̀ àti àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀ sàn Wọ́n sì tún ń bímọ Nítorí Ọlọ́run ti ṣé gbogbo ará ilé Ábímélékì nínú nítorí Sárà aya Ábúráhámù Ìbí Ísáákì Olúwa sì fi oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ hàn sí Ṣárà, sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ti sèlérí fún-un Ṣárà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní àkókò náà gan-an tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un Ábúráhámù sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sárà bí fun un ní Ísáákì Nígbà tí Ísáákì pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, Ábúráhámù sì kọ ọ́ ní ilà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún-un Ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún ni Ábúráhámù nígbà tí ó bí Ísáákì Ṣárà sì wí pé, Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi Ó sì fi kún un pé, Ta ni ó le sọ fún Ábúráhámù pé, Ṣárà yóò di ọlọ́mọ Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Ábúráhámù ní ìgbà ogbó rẹ Nígbà tí ọmọ náà dàgbà ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Ísáákì lẹ́nu ọmú, Ábúráhámù ṣe àsè ńlá Ṣùgbọ́n Ṣárà rí ọmọ Ágárì ará Éjíbítì tí ó bí fún Ábúráhámù tí ó fi ṣe ẹlẹ́yà, ó sì wí fún Ábúráhámù pé, Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Ísáákì pín ogún Ọ̀rọ̀ náà sì ba Ábúráhámù lọ́kàn jẹ́ gidigidi nítorí ọmọ rẹ̀ náà sáà ni Isìmàẹ́lì i ṣe Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fun un pé, Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ Gbọ́ ohun tí Ṣárà wí fún ọ, nítorí nípasẹ̀ Ísáákì ni a ó ti ka irú ọmọ rẹ̀ Èmi yóò sọ ọmọ ẹrúbìnrin náà di orílẹ̀ èdè pẹ̀lú, nítorí ọmọ rẹ ni Ábúráhámù sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mú oúnjẹ àti ìgò omi kan, ó sì kó wọn fún Ágárì, ó kó wọn lé e léjìká, ó sì lé e jáde pẹ̀lú ọmọ náà Ó sì lọ lọ́nà rẹ, ó sì ń ṣe alárìnkiri ní ijù Báá-Ṣébà Nígbà tí omi inú ìgò náà tan, ó gbé ọmọ náà sí abẹ́ igbó Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà , nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú Bí ó sì ti jókòó sí tòòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Ańgẹ́lì Ọlọ́run sì pe Ágárì láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, Ágárì, kín ni ó ṣe ọ́ Má bẹ̀rù nítorí Olúwa ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí Dìde, gbé ọmọ náà sókè, kí o sì dì í mú nítorí èmi yóò ṣọ ọmọ náà di orilẹ̀ èdè ńlá Ọlọ́run sì ṣí ojú Ágárì, ó sì rí kànga kan, ó lọ ṣíbẹ̀, ó rọ omi kún inú ìgò náà, ó sì fún ọmọ náà mu Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ìjù, ó sì di tafàtafà Nígbà tí ó ń gbé ni ihà ní Páránì, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Éjíbítì wá Ní àkókò yìí ni ọba Ábímélékì àti Píkólì, olórí ogun rẹ̀ wí fún Ábúráhámù pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fi hàn fún ọ pẹ̀lú Ábúráhámù sì wí pé, Èmí búra Nígbà náà ni Ábúráhámù fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn fún Ábímélékì nípa kànga tí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n Ábímélékì dáhùn pé, Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe èyí, ìwọ kò sì sọ fún mi tẹ́lẹ̀, òní ni mo sẹ̀sẹ̀ ń gbọ́ báyìí Ábúráhámù sì mú àgùntàn àti màlúù wá, ó sì kó wọn fún Ábímélékì Àwọn méjèèjì sì dá májẹ̀mú Ábúráhámù sì ya abo ọ̀dọ́-àgùtàn méje nínú agbo àgùntàn rẹ̀ sọ́tọ̀ Ábímélékì sì béèrè lọ́wọ́ Ábúráhámù pé, Kín ni ìtumọ̀ yíyà tí ìwọ ya àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn méje wọ̀nyí sọ́tọ̀ sí Ó da lóhùn pé Gba àwọn abo ọ̀dọ́-àgùtàn méje wọ̀nyí lọ́wọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí Nítorí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ náà ni Baa-Ṣébà nítorí níbẹ̀ ni àwọn méjèèjì gbé búra Lẹ́yìn májẹ̀mú tí wọ́n dá ní Báá-Ṣébà yìí ni Ábímélékì àti Píkólì olórí ogun rẹ̀ pada sí ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì Ábúráhámù sì gbin igi Támárísíkì kan sí Báá-Ṣébà, níbẹ̀ ni ó sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run ayérayé Ábúráhámù sì gbé ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì fún ọjọ́ pípẹ́ Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run dán Ábúráhámù wò, ó pè é, ó sì wí pé, Ábúráhámù Ábúráhámù sì dáhùn pé, Èmi nìyí Ọlọ́run sì wí pé, Mú ọmọ rẹ, àní Ísáakì ọmọ rẹ kan ṣoṣo o nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Móráyà, kí o sì fi rúbọ ṣíṣun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ Ábúráhámù sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Ísáákì ọmọ rẹ̀, ó sì ṣe igi fún ẹbọ ṣíṣun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún-un Nígbà tí ó di ọjọ kẹ́ta, Ábúráhámù gbé ojú sókè, ó sì rí ibi tí ó ń lọ ní òkèrè, Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ọ̀hún-un-nì láti sin Olúwa , a ó sì tún pada wá bá a yín Ábúráhámù sì gbé igi ẹbọ ṣíṣun náà ru Ísáákì, òun fúnra rẹ̀ sì mú iná àti ọ̀bẹ Bí àwọn méjèèjì ti ń lọ, Ísáákì sì sọ fún Ábúráhámù baba rẹ̀ wí pé, Baba mi Ábúráhámù sì da lóhùn pé, Èmi nìyí ọmọ mi Ísáákì sì tún wí pé, Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́ àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà Ábúráhámù sì dáhùn pé, Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ̀-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìn-àjò wọn Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igiọ lé e lórí, ó sì di Ísáákì ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà Ábúráhámù sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀ Ṣùgbọ́n ańgẹ́lì Olúwa ké sí i láti ọ̀run wí pé Ábúráhámù! Ábúráhámù! Ábúráhámù sì dáhùn pé, Èmi nìyí Ańgẹ́lì Olúwa sì wí pé, Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan soso dùn mi Ábúráhámù sì gbójú sókè, ó sì rí àgbò kan tí ó fi ìwo há pàǹtírí, ó sì lọ mú un, ó sì fi rú ẹbọ ṣíṣun, dípò ọmọ rẹ̀ Ábúráhámù sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, Olúwa yóò pèṣè Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, Ní orí òkè Olúwa , ni a ó ti pèsè Ańgẹ́lì Olúwa sì tún pe Ábúráhámù láti ọ̀run lẹ́ẹ̀kejì Ó sì wí pé, Olúwa wí pé, Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dùn mí, dájúdájú, Èmi yóò bùkún ọ, Èmi yóò sì mú kí ìran rẹ yìí kí ó pọ̀ bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí i yanrìn etí òkun Irú ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀ta wọn, àti nípaṣẹ̀ irú ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́ràn sí mi lẹ̀nu Nígbà náà ni Ábúráhámù padà tọ àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ lọ Gbogbo wọn sì padà lọ sí Báá-Ṣébà Ábúráhámù sì dúró ní Báá-Ṣébà Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni a wí fún Ábúráhámù pé, Mílíkà aya Náhórì bí àwọn ọmọkùnrin fún-un Úsì, àkọ́bí rẹ̀, Búsì arákùnri rẹ̀, Kémúélì Kéṣédì, Áṣọ̀, Pílídásì, Jídíláfù, àti Bétúélì Bétúélì sì ni baba Rèbékà Mílíkà sì bí àwọn ọmọ mẹ́jọ wọ̀nyí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù Àlè rẹ̀ tí ń jẹ́ Réhúmà náà bí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí fun un Tébà, Gáhámù, Táhásì àti Máákà Ikú Ṣárà Ṣárà sì pé ọmọ ọdún mẹ́tà-dín-láàádóje ó sì kú ní Kíríátì-Áríbà ní ilẹ̀ Kénánì, Ábúráhámù lọ láti sọ̀fọ̀ àti láti sunkún nítorí Ṣárà Ábúráhámù sì dìde lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú aya rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ará Hítì wí pé, Iwo jẹ́ àjèjì àti àlejò láàrin yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí Àwọn ará Hítì dá a lóhùn pé, Olúwa mi, gbọ́ tiwa, ó jẹ́ alágbára ọmọ-aládé láàrin wa, sin òkú rẹ sí ibojì tí ó dárajù nínú àwọn ibojì wa, kò sí ẹni tí yóò fi ibojì rẹ dùn ọ́ láti sin òkú rẹ sí Nígbà náà ni Ábúráhámù dìde, ó sì tẹríba níwájú àwọn ará ilẹ̀ náà-àwọn ará Hítì Ó sì wí fún wọn pé, Bí ó bá ṣe pé, lóòótọ́ ni ẹ fẹ́ kí n sin òkú mi kúrò nílẹ̀, ẹ gbọ́ tèmi, ẹ bá mi bẹ Éfúrónì ọmọ Ṣóhárì, kí ó ta ihò àpáta Mákípélà tí ó jẹ́ tirẹ̀ fún mi, èyí tí ó wà ni orí oko rẹ̀, kí ó tà á fún mi ni iye owó tí à ń ta irú rẹ̀ fún ilẹ̀ ìsìnkú láàrin yín Éfúrónì ará Hítì sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú, ó sì dá Ábúráhámù lóhùn lójú gbogbo àwọn ará ìlú tí ó wà níbẹ̀, lẹ́nu ibodè ìlú, pé, Rárá, Olúwa mi, Gbọ́ tèmi mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà níbẹ̀ Mo fún ọ níwájú gbogbo àwọn ènìyàn mi Sin òkú rẹ ṣíbẹ̀ Ábúráhámù sì tún tẹríba níwájú àwọn ènìyàn ìlú náà, Ó sì wí fún Éfúrónì lójú gbogbo wọn pé, Bí ìwọ bá fẹ́, gbọ́ tèmi, èmi yóò san owó ilẹ̀ náà, gbà á lọ́wọ́ mi kí n lè sin òkú mi ṣíbẹ̀ Éfúrónì sì dá Ábúráhámù lóhùn pé, Gbọ́ tèmi Olúwa mi, irínwó òsùwọ̀n owó fàdákà ni ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n kín ni ìyẹn já mọ láàrin àwa méjèèjì Ṣáà sin òkú ù rẹ Ábúráhámù sì gba ohun tí Éfúróni wí, ó sì wọn iye owó fàdákà náà lójú gbogbo ènìyàn irínwó owó idẹ fàdákà gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n oníṣòwò ayé ìgbà náà Báyìí ni ilẹ̀ Éfúrónì tí ó wà ni Mákípélà nítòòsí Mámúrè-ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ àti gbogbo igi tí ó wà nínú ilẹ̀ náà ni a ṣe ètò rẹ̀ dájú, bí ohun-ìní fún Ábúráhámù níwájú gbogbo ará Hétì tí ó wá sí ẹnu ibodè ìlú náà Lẹ́yìn náà ni Ábúráhámù sin aya rẹ̀ Sárà sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Mákípélà nítòòsí Mámúrè ní ilẹ̀ Kénánì Ilẹ̀ náà àti ihò-àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni àwọn ará Hítì fi fún Ábúráhámù gẹ́gẹ́ bí ohun ìní títí láé bí ilẹ̀ ìsìnkú fún àwọn òkú tí ó bá kú fun un Ísáákì àti Rèbékà Ábúráhámù sì ti darúgbó ní àkókò yìí, Olúwa sì ti bùkún fún-un ni gbogbo ọ̀nà, Ó wí fún olórí àwọn ìránṣẹ́ ilẹ̀ rẹ̀, tí ó jẹ́ alábojútó ohun gbogbo tí ó ní pé, Fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi Èmi yóò mú ọ búra lórúkọ Olúwa Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ kì yóò fẹ́ aya fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin ará Kénánì, láàrin àwọn ẹni tí èmi ń gbé Ṣùgbọ́n, ìwọ yóò lọ sí orílẹ̀-èdè mi, láàrin àwọn ará mi láti fẹ́ aya fún Ísáákì, ọmọ mi Ìránṣẹ́ náà bi í wí pé, Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ń kọ́ Ǹjẹ́ mo lè mú ọmọ rẹ padà lọ sí orílẹ̀-èdè níbi tí ìwọ ti wá Ábúráhámù sì wí fún un pé, Rí i dájú pé iwọ kò mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀ Olúwa , Ọlọ́run ọ̀run tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ baba mi àti ní ilẹ̀ tí a bí mi, tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tí ó sì búra fún mi pé, Irú ọmọ rẹ ni n ó fi ilẹ̀ yìí fún, yóò rán ańgẹ́lì rẹ̀ ṣáájú rẹ, kí ìwọ kí ó lè rí aya fẹ́ wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀ Bí obìnrin náà kò bá fẹ́ tẹ̀lé ọ wá, nígbà náà ni a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ìbúra yìí, ṣùgbọ́n pàtàkì ni pé ìwọ kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀ Ìránṣẹ́ náà sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí abẹ́ itan Ábúráhámù olúwa rẹ̀, ó sì búra fún nítorí ọ̀rọ̀ náà Ìránṣẹ́ náà sì mú ràkunmí mẹ́wàá, pẹ̀lú onírúurú ohun dáradára láti ọ̀dọ̀ olúwa rẹ̀, ó sì dìde ó sì lọ sí Aramu-Náháráímù, sí ìlú Náhórì, Ó sì mú àwọn ràkunmí náà kúnlẹ̀ nítòòsí kànga lẹ́yìn ìlú, ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ̀ ní àkókò tí àwọn obìnrin máa ń lọ pọn omi Ó sì gbàdúrà wí pé, Olúwa , Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa à mi jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, sì fi àánú hàn fún Ábúráhámù olúwa mi Kíyèsí i, mo dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ yìí, àwọn ọmọbìnrin ìlú yìí sì ń jáde wá pọn omi Jẹ́ kí ó ṣe pé nígbà tí mo bá wí fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin pe, Jọ̀wọ́ sọ ládugbó rẹ kalẹ̀, kí n le mu omi, tí ó bá sì wí pé, mu un, èmi ó sì fún àwọn ràkunmí rẹ náà mu pẹ̀lú, jẹ́ kí ó ṣe èyí tí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ Ísáákì Nípa èyí ni n ó fi mọ̀ pé o ti fi àánú hàn fún olúwa mi Kí o tó di pé, ó parí àdúrà, Rèbékà dé pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀ Ọmọ Bétúélì ni Bétúélì yìí ni Mílíkà bí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù Ọmọbìnrin náà rẹwà, wúndíá ni, kò sì tíì mọ ọkùnrin, ó lọ sí ibi ìsun omi náà, ó sì pọn omi sínú ìkòkò omi, ó sì gbé e, ó ń gòkè bọ̀ kúrò níbi omi Ìránṣẹ́ náà súré lọ pàdé e rẹ̀ ó sì wí fun un pé, Jọ̀wọ́ fún mi ni omi díẹ̀ nínú ìkòkò omi rẹ Òun náà dáhùn pé, Mu, olúwa mi, ó sì yára sọ ìkòkò omi náà ka ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún-un mu Lẹ́yìn tí ó ti fún un ni omi mu tán, ó wí pé, Èmi ó bu omi fún àwọn ràkunmí rẹ pẹ̀lú títí wọn yóò fi mu àmutẹ́rùn Ó sì yára da omi inú ìkòkò omi rẹ̀ sínú ìbùmu, ó sáré padà lọ síbi omi láti pọn sí i wá fún àwọn ràkunmí, títí tí ó fi pọn fún gbogbo wọn Láì sọ ọ̀rọ̀ kan, ìránṣẹ́ yìí ń wo ọmọbìnrin náà fínnífínní láti mọ̀ bóyá Ọlọ́run ti ṣe ìrìn-àjò òun ní rere tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ Lẹ́yìn tí àwọn ràkunmí náà ti mu omi tán, ni ọkùnrin náà mú òrùka wúrà ààbọ̀ ìwọn sékélì àti júfù méjì fún ọwọ́ rẹ̀, tí ìwọ̀n sékélì wúrà mẹ́wàá Lẹ́yìn náà, ó béèrè pé, Ọmọ ta ni ìwọ í ṣe Jọ̀wọ́ wí fún mi, ǹjẹ́ ààyè wà ní ilé baba rẹ láti wọ̀ sí ní alẹ́ yìí Ó dáhùn pé, Bétúélì ọmọ tí Mílíkà bí fún Náhórì ni baba mi Ó sì fi kún un pé, A ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ koríko àti oúnjẹ fún àwọn ràkunmí yín àti yàrá pẹ̀lú fún-un yín láti wọ̀ sí Nígbà náà ni ọkùnrin náà tẹríba, ó sì sin Olúwa Wí pe, Ògo ni fún Olúwa , Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa mi ti kò jẹ́ kí àánú àti òtítọ́ rẹ̀ kí ó yẹ̀ lọ́dọ̀ olúwa mi Ní ti èmi Olúwa ti darí ìrìn-àjò mi sí ilé ìbátan olúwa mi Ọmọbìnrin náà sì sáré, ó sì lọ sọ ohun gbogbo wọ̀nyí fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀ Rèbékà ní arákùnrin tí ń jẹ́ Lábánì Lábánì sì sáré lọ bá ọkùnrin náà ní etí odò Bí ó sì ti rí òrùka imú àti ẹ̀gbà ní ọwọ́ arábìnrin rẹ̀ tí ó sì tún gbọ́ ohun tí Rèbékà sọ pé ọkùnrin náà sọ fún òun, ó jáde lọ bá ọkùnrin náà, ó sì bá a, ó dúró ti ràkunmí wọ̀n-ọn-nì ní ẹ̀bá ìsun-omi Ó wí fún ọkùnrin náà pé, Wá, ìwọ ẹni ìbùkún Olúwa , Èéṣe tí o dúró sí ìta níhìn-ín Mo ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún ọ àti ààyè fún àwọn ràkunmí rẹ Ọkùnrin náà sì bá Lábánì lọ ilé, ó sì tú ẹrù orí ràkunmí rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fún wọn ni koríko àti oúnjẹ Ó sì bu omi fún ọkùnrin náà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ láti wẹ ẹsẹ̀ wọn Wọ́n sì gbé oúnjẹ ṣíwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n, ó wí pé, Èmi kò ní jẹun àyàfi bí mo bá sọ ohun tí mo níí sọ Lábánì sì wí pé, Kò burú, sọ ọ́ Nítorí náà ó wí pé, Ìránṣẹ́ Ábúráhámù ni èmi Olúwa sì ti bùkún olúwa mi gidigidi Ó sì ti di ọlọ́rọ̀, Ó sì ti fún-un ní àgùntàn, màlúù, àti fàdákà àti wúrà, ìránṣẹ́-kùnrin àti ìránṣẹ́-bìnrin àti ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣárà aya olúwa mi sì ti bí ọmọkùnrin kan fún un, ní ìgbà ogbó rẹ̀, olúwa mi sì ti fún ọmọ náà ní ohun gbogbo tí ó ní Olúwa mi sì ti mú mi búra wí pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrin àwọn ọmọbìnrin Kénánì, ní ilẹ̀ ibi tí èmi ń gbé, Ṣùgbọ́n lọ sí ìdílé baba mi láàrin àwọn ìbátan mi kí o sì fẹ́ aya fún ọmọ mi Mo sì bí olúwa mi léèrè pé, Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà kò bá fẹ́ bá mi wá ńkọ́ Ó sì dáhùn wí pé, Olúwa , níwájú ẹni tí èmi ń rìn yóò rán Ańgẹ́lì rẹ̀ ṣáájú rẹ yóò sì jẹ́ kí o ṣe aṣeyọrí ní ìrìn-àjò rẹ, kí ìwọ kí ó ba le fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrin àwọn ìbátan mi, àti láàrin àwọn ìdílé baba mi Nígbà tí ìwọ bá lọ sí ọ̀dọ̀ ìdílé baba mi , nígbà náà ni ìwọ tó bọ́ nínú ìbúra yìí Nígbà tí mo dé ibi ìsun omi lónìí, mo wí pé, Olúwa Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa mi, bí ìwọ bá fẹ́, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n ṣe àṣeyọ́rí lórí ohun tí mo bá wá yìí, Wò ó, mo dúró ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi yìí, kí ó ṣe pé, nígbà tí wúndíá kan bá jáde wá pọn omi, tí èmi sì wí fún un pé, Jọ̀wọ́ fún mi ní ìwọ̀nba omi díẹ̀ mu nínú ládugbó rẹ, tí ó bá sì wí fún mi pé, Mu ún, èmi yóò sì tún pọn omi fún àwọn ràkunmí rẹ pẹ̀lú, Jẹ́ kí ẹni náà jẹ́ ẹni tí Olúwa yàn fún ọmọ Ábúráhámù, olúwa mi Kí n sì tó gbàdúrà tán nínú ọkàn mi, Rèbékà jáde wá pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀, ó sì lọ sí ibi ìsun omi ó sì pọn omi Mo sì wí fun un pé, Jọ̀wọ́ fún mi ni omi mu Kíákíá ni ó sọ ìkòkò rẹ̀ kalẹ̀ láti èjìká rẹ̀, ó sì wí fún mi pé, Mu ún, èmi yóò sì tún fún àwọn ràkúnmí rẹ mu pẹ̀lú Mo sì mu, ó sì tún fún àwọn ràkúnmí mi mu pẹ̀lú Mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ọmọ ta ní ìwọ í ṣe Ó sì wí fún mi pé, ọmọbìnrin Bétúélì tí í ṣe ọmọ Náhórì ni òun, Mílíkà sì ni ìyá òun Nígbà náà ni mo fi òrùka náà bọ imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà-ọwọ́ náà si ní ọwọ́ Mo sì wólẹ̀ mo sì sin Olúwa , Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa à mi, ẹni tí ó ṣe amọ̀nà mi láti rí ọmọ ọmọ arákùnrin olúwa mi, mú wá fún ọmọ rẹ̀ Ǹjẹ́ nísin yìí bí ẹ̀yin yóò bá fi inú rere àti òtítọ́ bá olúwa mi lò, ẹ sọ fún mi, bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, ẹ sọ fún mi, kí ó le è mọ ọ̀nà tí èmi yóò yà sí Lábánì àti Bétúélì sì dáhùn pé, Lọ́dọ̀ Olúwa ni èyi ti wá, nítorí náà àwa kò le sọ rere tàbí búburú fún ọ Rèbékà nìyí, mu un kí ó má a lọ, kí ó sì di aya ọmọ olúwa à rẹ, bí Olúwa ti fẹ́ Nígbà tí ọmọ-ọ̀dọ̀ Ábúráhámù gbọ́ ohun tí wọ́n wí, ó wólẹ̀ níwájú Olúwa Nígbà náà ni ó kó ohun èlò wúrà àti fàdákà jáde àti aṣọ, ó sì fi wọ́n fún Rèbékà, ó fún arákùnrin Rèbékà àti ìyá rẹ̀ ní ẹ̀bùn olówó iyebíye pẹ̀lú Lẹ́yìn náà ni òun àti àwọn ọkùnrin tí ó bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, tí wọn sì sùn níbẹ̀ ní òru ọjọ́ náà Bí wọ́n ti dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó wí pé, Ẹ rán mi padà lọ sí ọ̀dọ̀ olúwa mi Ṣùgbọ́n arákùnrin Rèbékà àti ìyá rẹ̀ fèsì pé, A fẹ́ kí Rèbékà wà pẹ̀lú wa fún nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá sí i, lẹ́yìn ìyẹn, ìwọ le máa mu lọ Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, Ẹ má ṣe dá mi dúró, Olúwa ṣáà ti ṣe ọ̀nà mi ní rere Ẹ rán mi lọ, kí èmi kí ó le è tọ olúwa à mi lọ Nígbà náà ni wọ́n sọ pé, Jẹ́ kí a pe ọmọ náà gan-an kí a sì bi í Wọ́n sì pe Rèbékà wọ́n sì bi í, wí pé, Ṣe ìwọ yóò bá ọkùnrin yìí lọ Ó sì dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni, èmi yóò lọ Wọ́n sì gbà kí Rèbékà àti olùtọ́jú rẹ̀, pẹ̀lú ìránṣẹ́ Ábúráhámù àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ má a lọ Wọ́n sì súré fún Rèbékà, wọn sì wí fun un pé, Arábìnrin wa, ìwọ yóò di ìyá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún Ǹjẹ́ kí àwọn irú-ọmọ rẹ kí ó gba ibodè ọ̀ta a wọn Nígbà náà ni Rèbékà àti àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ múra, wọn sì gun àwọn ràkunmí, wọ́n sì bá ọkùnrin náà padà lọ Ìránṣẹ́ náà sì mú Rèbékà ó sì bá tirẹ̀ lọ Ísáákì sì ń ti Bia-Lahai-Róì bọ, nítorí ìhà gúsù ni ó ń gbé Ísáákì sáà jáde lọ sí oko ni ìrọ̀lẹ́ láti ṣe àsàrò, bí ó sì ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ràkunmí tí ń bọ̀ wá Rèbékà pẹ̀lú sì gbójú sókè, ó sì rí Ísáákì Ó sọ̀kalẹ̀ lórí ràkunmí, Ó sì béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ náà wí pé, Ta ni ọkùnrin tí ń bọ̀ wá pàdé wa láti inú oko Ìránṣẹ́ náà sì wí fun un pé, Olúwa mi ni, nítorí náà ni Rèbékà mú ìbòjú, ó sì bo ojú rẹ̀ Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà ròyìn fún Ísáákì ohun gbogbo tí ó ti ṣe Nígbà náà ni Ísáákì mú Rèbékà wọ inú àgọ́ ọ ìyá rẹ̀, Ṣárà, ó sì di aya rẹ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ó sì jẹ́ ìtùnú fún Ísáákì lẹ́yìn ikú ìyá rẹ̀ Ikú Ábúráhámù Ábúráhámù sì tún fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kétúrà Ó sì bí Ṣímúránì, Jókíṣánì, Médánì, Mídíánì, Ísíbákù, àti Ṣúà Jókíṣánì ni baba Ṣébà àti Dédánì, àwọn ìran Dédánì ni àwọn ara Áṣúrímù, Létúsì àti Léúmínù Àwọn ọmọ Mídíánì ni Éfánì, Éférì, Ánókù, Ábídà àti Élídà Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Kétúrà Ábúráhámù sì fi ohun gbogbo tí ó ní fún Ísáákì Ṣùgbọ́n kí o tó kú, ó fún àwọn ọmọ tí àwọn àlè rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn, ó sì lé wọn jáde lọ fún Ísáákì ọmọ rẹ sí ilẹ̀ ìlà oòrùn Gbogbo àpapọ̀ ọdún tí Ábúráhámù lò láyé jẹ́ igba ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n Ábúráhámù sì kú ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ Ó dàgbà, ó darúgbó kí ó tó kú A sì sin in sí ibojì àwọn ènìyàn rẹ̀ Àwọn ọmọ rẹ̀, Ísáákì àti Ísímáélì sì sin-in sínú ihò àpáta ni Mákípélà ní ẹ̀gbẹ́ Mámúrè, ní oko Éfúrónì ọmọ Ṣóhárì ara Hítì Inú oko tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ ara Hítì yìí ni a sin Ábúráhámù àti Ṣárà aya rẹ̀ sí Lẹ́yìn ikú Ábúráhámù, Ọlọ́run sì bùkún fún Ísáákì ọmọ rẹ̀, tí ó ń gbé nítòòsí orísun omi Bia-Lahai-Róì ní ìgbà náà Wọ̀nyí ni ìran Íṣímáélì, ọmọ Ábúráhámù ẹni tí Hágárì ará Éjíbítì, ọmọ ọ̀dọ̀ Ṣárà bí fún un Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Íṣímáélì bí a ṣe bí wọn, bẹ̀rẹ̀ láti orí Nébáótì tí í ṣe àkọ́bí, Kédárì, Ábídélì, Míbísámù, Mísímà, Dúmà, Máṣà, Hádádì, Témà, Jétúrì, Náfísì, àti Kédémà Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọ-ọba méjìlá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn Àpapọ̀ ọdún tí Íṣímáélì lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje ọdún, a sì sin in pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbégbé Áfílà títí tí ó fi dé Súrì, lẹ́bàá ààlà Éjíbítì bí ènìyàn bá ṣe ń lọ sí Áṣíríà Wọn kò sì gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn Wọ̀nyí ni ìtàn ìran Ísáákì ọmọ Ábúráhámù Ábúráhámù bí Ísáákì Nígbà tí Ísáákì di ọmọ ogójì ọdún ni ó gbé Rèbékà ọmọ Bétúélì ará Árámíà ti Padani-Árámù tí í ṣe arábìnrin Lábánì ará Árámíà ní ìyàwó Ísáákì sì gbàdúrà sì Olúwa , nítorí aya rẹ̀ tí ó yàgàn, Olúwa sì gbọ́ àdúrà rẹ̀, Rèbékà sì lóyún Àwọn ọmọ náà ń gbún ara wọn nínú rẹ̀, ó sì wí pé, Èéṣe tí èyí ń ṣẹlẹ̀ sí mi, ó sì lọ béèrè lọ́dọ̀ Olúwa Olúwa sì wí fún un pé, Orílẹ̀ èdè méjì ni ń bẹ nínú rẹ, àwọn méjì tí ó jáde láti inú rẹ yóò sì pínyà, àwọn ènìyàn kan yóò jẹ́ alágbára ju èkejì lọ, ẹ̀gbọ́n yóò sì máa sin àbúrò Nígbà tí ó tó àkókò fun un láti bímọ, ìbejì ni ó wà nínú rẹ̀, ọkùnrin sì ni wọ́n Èyí tí ó kọ jáde jẹ́ ọmọ pupa, irun sì bo gbogbo ara rẹ̀ bí aṣọ onírun, nítorí náà, wọ́n pè é ní Ísọ̀ Lẹ́yìn rẹ̀ ni èyí èkejì jáde, ó sì di arákùnrin rẹ̀ ni gìgíṣẹ̀ mú, nítorí náà ni wọn ṣe pe orúkọ rẹ ni Jákọ́bù Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Ísáákì, nígbà tí Rèbékà bí ìbejì yìí fún un Àwọn ọmọkùnrin náà sì dàgbà Ísọ̀ sì di ọlọ́gbọ́n ọdẹ, ẹni tí ó fẹ́ràn àti máa dúró ní oko Jákọ́bù sì jẹ́ ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí ó ń gbé láàrin ìlú Ísáákì, ẹni tí ó fẹ́ràn ẹran-ìgbẹ́ fẹ́ràn Ísọ̀ nítorí ẹran ìgbẹ́ tí Éṣáù máa ń pa, ṣùgbọ́n Rèbékà fẹ́ràn Jákọ́bù Ní ọjọ́ kan, Jákọ́bù ń ṣe oúnjẹ, Éṣáù sì ti igbó ọdẹ dé, ó sì ti rẹ̀ ẹ́ Ó wí fún Jákọ́bù pé, Ṣe kánkán, fún mi jẹ lára àsáró rẹ pupa yìí, nítorí ebi ń pa mi gidigidi Jákọ́bù dáhùn pé, Kò burú, ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ fún mi ná Éṣáù sì dáhùn pé, Wò ó mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú, àǹfààní kín sì ni ogún ìbí jẹ́ fún mi Ṣùgbọ́n, Jákọ́bù dáhùn pé, Kọ́kọ́ búra fún mi pé tèmi ni ogún ìbí náà yóò jẹ́ Báyìí ni Ísọ̀ búra tí ó sì gbé ogún ìbí rẹ̀ tà fún Jákọ́bù Nígbà náà ni Jákọ́bù fún Ísọ̀ ní oúnjẹ àti ọbẹ̀ Ó jẹ ẹ́, ó sì jáde lọ Báyìí ni Ísọ̀ ṣe aláìka ogún ìbí rẹ̀ sí Ísáákì àti Ábímélékì Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ fún èyí tí ó mú ní ìgbà ayé Ábúráhámù, Ísáákì sì lọ sọ́dọ̀ Ábímélékì ọba àwọn Fílístínì ni Gérárì Olúwa sì fi ara han Ísáákì, ó sì wí pé, Má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì Jókòó ní ilẹ̀ tí èmi sọ fún ọ Dúró ní ilẹ̀ yìí fún ìgbà díẹ̀, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ, Èmi yóò sì bùkún ọ Nítorí ìwọ àti irú ọmọ rẹ ni èmi yóò fi gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí fún, èmi yóò sì fi ìdí ìbúra tí mo ṣe fún Ábúráhámù baba rẹ mulẹ̀ Èmi yóò sọ ìran rẹ di púpọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, n ó sì fún wọn ní àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí, nípaṣẹ̀ irú ọmọ rẹ ni a ó sì bùkún fún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé, nítorí pé Ábúráhámù gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, ó sì pa gbogbo ìkìlọ̀, àṣẹ, ìlànà àti òfin mi mọ́ Nítorí náà Ísáákì dúró ní Gérárì Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà béèrè bí t'òun àti ti Rèbékà ti jẹ́, ó dáhùn pé, arábìnrin òun ní í ṣe nítorí pé ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ wí pé aya òun ni ó ń rò ó wí pé wọ́n le pa òun nítorí Rèbékà, nítorí ti Rèbékà lẹ́wà púpọ̀ Nígbà tí Ísáákì sì ti wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, Ábímélékì ọba Fílístínì yọjú lójú fèrèsé, ó sì rí Ísáákì ń bá Rèbékà aya rẹ̀ tage Nígbà náà ni Ábímélékì ránṣẹ́ pe Ísáákì ó sì wí fun pé, Nítòótọ́, aya rẹ ni obìnrin yìí í ṣe, èéṣe tí o fi pè é ní arábìnrin rẹ Ísáákì sì fèsì pé, Nítorí mo rò pé mo le pàdánù ẹ̀mí mi nítorí rẹ̀ Nígbà náà ni Ábímélékì dáhùn pé, Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá ti bá a lò pọ̀ ńkọ́ Ìwọ ìbá wá mú ẹ̀bi wá sórí wa Nígbà náà ni Ábímélékì pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin yìí tàbí aya rẹ̀ yóò jẹ̀bi ikú Ní ọdún náà, Ísáákì gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rọ̀rún ni ọdún kan náà nítorí Ọlọ́run bùkún un Ó sì di ọlọ́rọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ọlọ́rọ̀ gidigidi Ó ní ọ̀pọ̀lopọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn Fílístínì ń ṣe ìlara rẹ̀ Nítorí náà àwọn ará Fílístínì ru erùpẹ̀ di gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Ábúráhámù baba rẹ̀ ti gbẹ́ Nígbà náà ni Ábímélékì wí fún Ísáákì pé, Jáde kúrò ní ilẹ̀ wa, nítorí tí ìwọ ti di alágbára púpọ̀ jù wá lọ Ísáákì sì sí kúrò níbẹ̀, ó sì pàgọ́ sí àfonífojì Gérárì ó sì ń gbé ibẹ̀ Ísáákì sì ṣe àtúngbẹ́ àwọn kànga tí baba rẹ̀ ti gbẹ́ nígbà ayé rẹ̀, èyí tí àwọn Fílístínì ti dí lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, ó sì fún wọn lórúkọ tí baba rẹ̀ ti sọ wọ́n tẹ́lẹ̀ Àwọn ìránṣẹ́ Ísáákì sì gbẹ́ kànga ní àfonífojì náà, wọ́n kan ìsun omi níbẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn darandaran Gérárì ń bá àwọn darandaran Ísáákì jà sí kànga náà pé àwọn ni àwọn ni ín Nítorí náà ni ó fi pe orúkọ kànga náà ní Éṣékì, nítorí pé wọ́n bá a jà sí kànga náà Àwọn ìránṣẹ́ Isáákì tún gbẹ́ kànga mìíràn, wọ́n sì tún jà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ṣìtínà Ó sì tún kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga mìíràn, wọn kò sì já sí èyí rárá, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Réhóbótì, ó wí pé, Nísinsìnyìí, Olúwa ti fi àyè gbà wá, a ó sí i gbilẹ̀ sì ni ilẹ̀ náà Láti ibẹ̀, ó kúrò lọ sí Bíáṣébà Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, Olúwa sì fara hàn-án, ó sì wí pé, Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù baba rẹ Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Ábúráhámù ìránṣẹ́ mi Ísáákì sì kọ́ pẹpẹ kan ṣíbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan ṣíbẹ̀ Nígbà náà ni Ábímélékì tọ̀ ọ́ wá láti Gérárì, àti Áhúsátì, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fíkólì, olórí ogun rẹ̀ Ísáákì sì bi wọ́n léèrè pé, Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yin Wọ́n dáhùn pé, A rí i dájú pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nítorí náà ni a fi rò ó wí pé, ó yẹ kí májẹ̀mú kí o wà láàrin àwa àti ìwọ Jẹ́ kí a ṣe àdéhùn pé ìwọ kì yóò ṣe wá ní ibi, bí àwa pẹ̀lú kò ti ṣe ọ́ ní aburú, tí a sì ń ṣe ọ́ dáradára, tí a sì rán ọ jáde ní àlàáfíà láì ṣe ọ́ ní ibi, kíyèsi Olúwa sì ti bùkún fún ọ Ísáákì sì ṣe àsè fún wọn, wọn sì jẹ, wọ́n sì mu Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì wọn búra fún ara wọn Ísáákì sì rán wọn lọ, wọ́n sì lọ ní àlàáfíà Ní ọjọ́ náà gan-an ni àwọn ìránṣẹ́ Ísáákì wá sọ fún un pé àwọn ti kan omi ní kànga kan tí àwọn gbẹ́ Ó sì pe orúkọ kànga náà ní Ṣébà , títí di òní olónìí, orúkọ ìlú náà ni Bíáṣébà Nígbà tí Ísọ̀ pé ọmọ ogójì ọdún ó fẹ́ ọmọbìnrin kan tí a ń pè ní Júdíìtì, ọmọ Béérì, ará Hítì, ó sì tún fẹ́ Báṣémátì, ọmọ Élónì ará Hítì Fífẹ́ tí a fẹ́ àwọn obìnrin wọ̀nyí jẹ́ ìbànújẹ́ fún Ísáákì àti Rèbékà Ísáákì Súre fún Jákọ́bù Nígbà ti Ísáákì di arúgbó, ojú rẹ̀ sì ti di bàìbàì tóbẹ́ẹ̀ tí kò le ríran Ó pe Ísọ̀ àkọ́bí rẹ̀, ó sì wí fún un pé, Ọmọ mi, Ísọ̀ sì dáhùn pé, Èmi nìyí Ísáákì sì wí pé, Nísinsin yìí mo di arúgbó, èmi kò sì mọ ọjọ́ tí èmi yóò kú Nítorí náà, mú ohun èlò ọdẹ rẹ—apó àti ọrún—nísinsin yìí kí o sì lọ pa ẹran wá fún mi nínú igbó Kí o sì ṣe ẹran àdídùn fún mi, irú èyí tí mo fẹ́ràn kí o gbe wá fún mi kí n jẹ, kí n sì súre fún ọ kí n tó kú Ṣùgbọ́n Rèbékà ń rfetí léko gbọ́ nígbà tí Ísáákì ń bá Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ Nítorí náà, nígbà ti Ísọ̀ ti ṣe ọdẹ lọ sínú igbó, Rèbékà sọ fún Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ pé, Wò ó, mo gbọ́ tí baba rẹ ń bá ẹ̀gbọ́n rẹ sọ̀rọ̀ pé, Pa ẹran fún mi wá, kí o sì se oúnjẹ àdídùn fún mi láti jẹ, kí n baà le súre fún ọ níwájú Olúwa kí èmi tó kú Nísinsin yìí ọmọ mi, gbọ́ tèmi kí o sì ṣe ohun tí èmi yóò wí fún ọ Lọ sínú agbo ẹran, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì, kí ó lè ṣe oúnjẹ́ àdídùn fún baba rẹ, irú èyí tí ó fẹ́ràn dáradára Ìwọ yóò sì gbé e tọ baba rẹ lọ, kí òun baà lè jẹ ẹ́, kí ó sì súre fún ọ kí ó tó kú Jákọ́bù sì wí fún Rèbékà ìyá rẹ̀ pé, Ṣùgbọ́n Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n mi jẹ́ ènìyàn onírun lára bẹ́ẹ̀ alára ọ̀bọ̀rọ́ ni mi, Bí baba mi bá fọwọ́ kàn mi ńkọ́ Èmi yóò jọ ẹlẹ́tàn lójú rẹ̀, dípò kí ó súre fún mi, èmi yóò sì mú ègún wá sórí ara mi Mọ̀mọ́ rẹ̀ wá wí fun un pé, Ọmọ mi jẹ́ kí ègún náà wá sórí mi, ṣáà ṣe ohun tí mo wí kí o sì mú àwọ̀ ẹran náà wá fún mi Jákọ́bù sì ṣe ohun gbogbo tí ìyá rẹ̀ wí fun un, Rèbékà sì se oúnjẹ àdídùn náà, irú èyí tí Ísáákì fẹ́ràn Nígbà náà ni Rèbékà mú èyí tí ó dára jù nínú aṣọ Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ àgbà tí ó wà nínú ilé Rèbékà, ó sì fi wọ Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ kékeré Ó sì fi awọ ewúrẹ́ wọ̀n-ọn-nì bo ọwọ́ àti ibi tí ó yọ silẹ̀ lọ́rùn rẹ̀ tí kò ní irun Nígbà náà ni ó gbé ẹran dídùn náà àti oúnjẹ tí ó ti sè lé Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ Jákọ́bù wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, Baba mi, Baba rẹ sì dáhùn pé, Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi Jákọ́bù sì fèsì pé, Èmi ni Ísọ̀ àkọ́bí rẹ, mo ti ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí, jọ̀wọ̀ dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran-igbó mi tí mo ti sè, kí o ba à le súre fún mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ Ísáákì tún béèrè pé, Ọmọ mi, báwo ni ó ṣe tètè yá ọ bẹ́ẹ̀ Jákọ́bù sì tún dáhùn pé, Olúwa Ọlọ́run rẹ ló fún mi pa Nígbà náà ni Ísáákì wí fún Jákọ́bù pé, Súnmọ́ mi, kí n le è fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Ísọ̀ ọmọ mi ni ní tòótọ́ tàbí òun kọ́ Jákọ́bù sì súnmọ Ísáákì baba rẹ̀ Ísáákì sì fọwọ́ kàn-án, ó sì wí pé, Ohùn ni ohùn Jákọ́bù ṣùgbọ́n ọwọ́ ni ọwọ́ Ísọ̀ Kò sì dá Jákọ́bù mọ̀ nítorí ọwọ́ rẹ̀ nírun bí i ti Ísọ̀ arákùnrin rẹ, nítorí náà, ó súre fún-un ó sì bi í léèrè pé, Ǹjẹ́ ìwọ ni Éṣáù ọmọ mi ni tòótọ́ Jákọ́bù sì dáhùn pé, Èmi ni Nígbà náà ni Ísáákì wí pé Gbé ẹran igbó náà súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, kí èmi kí ó jẹ ẹ́, kí èmi sì súre fún ọ láti inú ọkàn mi wá Jákọ́bù sì gbé e wá ó sì jẹ ẹ́, ó sì tún fún-un ní wáìnì, ó sì mú un pẹ̀lú Nígbà náà ni Ísáákì baba rẹ̀ wí fun un pé, Súnmọ mi, ọmọ mi, kí o sì fẹnu kò mí ní ẹnu Ó sì súnmọ ọn, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnu Nígbà tí Ísáákì gbọ́ òórùn aṣọ rẹ̀, ó súre fún-un ó wí pé Wò ó òórùn ọmọ mi Dà bí òórùn oko tí Olúwa ti bùkún Kí Olúwa kí ó fún ọ ní ìrì ọ̀run àti nínú ọ̀rá ilẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti wáìnì túntún Kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó máa sìn ọ́, kí àwọn ènìyàn sì máa tẹríba fún ọ, máa ṣe olórí àwọn arákùnrin rẹ, kí àwọn ìyekan rẹ sì máa wólẹ̀ fún ọ Ègún ni fún gbogbo ẹni tí ń fi ọ́ ré, Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó súre fún ọ Bí Ísáákì ti súre tan tí Jákọ́bù ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Ísọ̀ ti oko ọdẹ dé Òun pẹ̀lú ṣe ẹran dídùn, ó sì gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, Baba mi, dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó tí mo ti ṣè, kí o sì súre fún mi Ìsáákì baba rẹ̀ sì bi í wí pé, Ìwọ ta ni Ó sì dáhùn pé Èmi Ísọ̀, àkọ́bí rẹ ni Nígbà náà ni Ísáákì wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé Mo sì ti súre fún un sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un Nígbà tí Ísọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ baba rẹ̀, ó ké, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún kíkorò, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, Baba mi súre fún èmi náà, àní fún èmi náà pẹ̀lú Ṣùgbọ́n Ísáákì wí pé, Àbúrò rẹ ti fi ẹ̀tàn wá, ó sì ti gba ìbùkún rẹ lọ Ísọ̀ sì wí pé, Lásán ni a pe orúkọ rẹ̀ ní Jákọ́bù, bí Ní ìgbà méjì yìí ni ó ti tàn mí jẹ ní àkọ́kọ́, ó gba ogún ìbí mi, nísinsinyìí, ó tún gba ìbùkún mi! Áà! Baba mi, ṣe o kò wá fi ìre kankan sílẹ̀ fun mi ni Ísáákì sì dá Ísọ̀ lóhùn pé, Mo ti fi ṣe olórí rẹ àti àwọn ìbátan rẹ ni mo fi ṣe ìránṣẹ́ fún-un, àti oúnjẹ àti wáìnì ni mo ti fi lé e lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, kí ni ó tún kù tí ǹ bá tún fún ọ báyìí ọmọ mi Ísọ̀ sì wí fún baba rẹ̀ pé, Ṣe ìre kan ṣoṣo ni ìwọ ní lẹ́nu ni baba mi , Ṣúre fún èmi náà, baba mi Ísọ̀ sì sunkún kíkankíkan Ísáákì bàbá rẹ̀ sì dá a lóhùn pé, Ibùjòkòó rẹ yóò jìnnà sí ọ̀rá ilẹ̀, àti sí ìrì ọ̀run láti òkè wá Nípa idà ni ìwọ yóò máa gbé, ìwọ yóò sì máa sin àbúrò rẹ, ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, nígbà tí ìwọ bá di alágbára ìwọ yóò já àjàgà rẹ̀-kúrò lọ́rùn rẹ ìwọ yóò sì di òmìnira Ísọ̀ sì kóríra Jákọ́bù nítorí ìre tí baba rẹ̀ sú fún un, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, Baba mi ṣáà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú, nígbà náà ni èmi ó pa Jákọ́bù, arákùnrin mi Nígbà tí Rèbékà sì gbọ́ ohun tí Ísọ̀ àkọ́bí rẹ̀ wí, ó sì ránṣẹ́ sí Jákọ́bù, ó sì wí fun un pé, Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ ń tu ara rẹ̀ nínú pẹ̀lú èrò àti pa ọ́ Nítorí náà ọmọ mi, ṣe ohun tí èmi yóò sọ fún ọ Ṣá lọ sọ́dọ̀ Lábánì ẹ̀gbọ́n mi ní Háránì Dúró sí ibẹ̀ títí di ìgbà tí inú Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ yóò fi rọ̀ Nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ kò bá bínú sí ọ mọ́, tí ó sì ti gbàgbé ohun tí ìwọ ṣe sí i, èmí ó ránṣẹ́ sí ọ láti padà wá, Èéṣe tí èmi ó fi pàdánù ẹ̀yin méjèèjì ní ọjọ́ kan náà Nígbà náà ni Rèbékà wí fún Isaaki pé, Ayé sì sú mi nítorí àwọn ọmọbìnrin Hétì wọ̀nyí Bí Jákọ́bù bá fẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Hétì wọ̀nyí, ó kúkú sàn kí n má wà láàyè Àlá Jákọ́bù ní Bẹ́tẹ́lì Nítorí náà Ísáákì pe Jákọ́bù, ó sì súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọbìnrin Kénánì Dípò bẹ́ẹ̀ lọ sí Padani-Árámù, sí ilé Bétúélì, baba ìyá rẹ, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ aya fún ara rẹ nínú àwọn ọmọbìnrin Lábánì arákùnrin ìyá rẹ Kí Ọlọ́run Olódùmarè kí ó bùkún fún ọ, kí ó sì mú ọ bí sí i, kí ó sì mú ọ pọ̀ sí i ní iye títí tí ìwọ yóò di àgbájọ àwọn ènìyàn Kí Ọlọ́run kí ó fún ìwọ àti irú ọmọ rẹ ní ìre tí ó sú fún Ábúráhámù, kí ìwọ kí ó le gba ilẹ̀ níbi tí a ti ń ṣe àtìpó yìí, ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún Ábúráhámù Bẹ́ẹ̀ ni Ísáákì sì rán Jákọ́bù lọ Ó sì lọ sí Padani-Árámù, lọ́dọ̀ Lábánì ọmọ Bétúélì, ará Árámíà, tí í ṣe arákùnrin Rèbékà ìyá Jákọ́bù àti Ísọ̀ Nígbà tí Ísọ̀ gbọ pé, Ísáákì ti ṣúre fún Jákọ́bù, ó sì ti ran Jákọ́bù lọ sí Padani-Árámù láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó ṣúre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kénánì àti pé, Jákọ́bù ti gbọ́ràn sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Árámù Nígbà náà ni Ísọ̀ mọ bí Ísáákì baba rẹ ti kórìíra àwọn ọmọbìnrin Kénánì tó Nítorí náà ó tọ Íṣímáélì lọ, ó sì fẹ́ Máhálátì, arábìnrin Nébájótù, ọmọbìnrin Ísímáélì tí í ṣe ọmọ Ábúráhámù Ó fẹ́ ẹ, kún àwọn ìyàwó tí ó ti ní tẹ́lẹ̀ Jákọ́bù kúrò ní Bíáṣébà, ó sì kọrí sí ìlú Áránì Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń sú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀ Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, Èmi ni Olúwa , Ọlọ́run Baba rẹ Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísáákì, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, àti dé gúsù àti àríwá A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé nípaṣẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ Nígbà tí Jákọ́bù jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀ Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi Ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí Jákọ́bù sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí òpó, ó sì da òróró si lórí Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lúsì tẹ́lẹ̀ rí Jákọ́bù sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀, tí mo sì padà sílé baba mi ní àlàáfíà, nígbà náà Olúwa ni yóò jẹ́ Ọlọ́run mi, Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ̀n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, gbogbo ohun tí O bá sì fún mi, èmi yóò fún Ọ ní ìdámẹ́wàá rẹ̀ Jákọ́bù dé Padani-Árámù Jákọ́bù sì tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìn-àjò rẹ̀, ó sì dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà oòrùn Ó sì rí kànga kan ní pápá, agbo àgùntàn mẹ́ta sì dúró láti mu omi ní ibi kànga náà, nítorí pé láti-inú kànga náà ni wọ́n ti ń fi omi fún agbo àgùntàn Òkúta tí a gbé dí ẹnu kànga náà sì tóbi gidigidi Nígbà tí gbogbo agbo ẹran bá péjọ pọ̀ sí ibẹ̀ tán ni àwọn darandaran yóò tó yí òkúta náà kúrò, tí wọn yóò sì fún àwọn ẹran náà ní omi, tí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, wọn yóò tún yí òkúta náà padà sí ẹnu kànga náà Jákọ́bù béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá Àwọn náà sì dáhùn pé, Láti Áránì ni, Ó sì bi wọ́n pé, Ǹjẹ́ ẹ mọ Lábánì ọmọ-ọmọ Náhórì Wọ́n sì dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni, àwa mọ̀ ọ́n Jákọ́bù béèrè pé, Ṣe àlàáfíà ni ó wà Wọ́n sì dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni Wò ó, Rákélì ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn Ó sì wí pé, Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì sú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀ Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun Wọ́n dá a lóhùn pé, Àwa kì í yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga láti pọn omi fún àwọn ẹran títí gbogbo àwọn darandaran àti àwọn ẹran yóò fi péjọ tán Bí wọ́n sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rákélì dé pẹ̀lú agbo àgùntàn baba rẹ̀, nítorí darandaran ni òun náà Nígbà tí Jákọ́bù rí Rákélì ọmọbìnrin Lábánì tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Lábánì, Jákọ́bù súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Lábánì ní omi Jákọ́bù sì fẹnu ko Rákélì ní ẹnu Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún Jákọ́bù sì wí fún Rákélì pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ Rèbékà Rákélì sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀ Ní keté tí Lábánì gbúròó Jákọ́bù ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé Jákọ́bù, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé Nigbà náà ni Jákọ́bù ròyìn ohun gbogbo fún un Lábánì sì wí pé, Ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ ara mi ni ìwọ jẹ́ Lẹ́yìn tí Jákọ́bù sì wà pẹ̀lú rẹ̀ fún odidi oṣù kan, Lábánì wí fún Jákọ́bù pé Bí a tilẹ̀ jẹ́ ìbátan, kò yẹ kí o máa ṣiṣẹ́ fún mi lásán láìgba ohun kankan Sọ ohun tì ìwọ fẹ́ gbà fún iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún mi! Wàyí o, Lábánì ní ọmọbìnrin méjì, orúkọ èyí ẹgbọ́n ń jẹ́ Líà, orúkọ àbúrò sì ń jẹ́ Rákélì Líà kò ní ẹwà púpọ̀, ṣùgbọ́n Rákélì ní ẹwà gidigidi Ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra Jákọ́bù sì fẹ́ràn Rákélì, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, Èmi yóò ṣiṣẹ́ sìn ọ fún ọdún méje, bí ìwọ yóò bá fún mi ní Rákélì ọmọ rẹ ní aya Lábánì sì dáhùn wí pé, Ó kúkú sàn kí ń fi fún ọ, ju kí ń fi fún ẹlòmíràn lọ, nítorí wà ní ọ̀dọ̀ mi Jákọ́bù sì ṣiṣẹ́ sin Lábánì fún ọdun méje láti fẹ́ Rákélì Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dà bí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀ Jákọ́bù sì wí fún Lábánì pé, Mo ti parí àsìkò tí a jọ ṣe àdéhùn rẹ̀, nítorí náà fún mi ní aya mi, kí òun lè ṣe aya fún mi Lábánì sì pe gbogbo ènìyàn ibẹ̀ jọ, ó sì ṣe àṣè ìyàwó fún wọ́n Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru, Lábánì mú Líà tọ Jákọ́bù lọ Jákọ́bù sì bá a lòpọ̀ Lábánì sì fi Ṣílípà ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Líà gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jákọ́bù rí i pé Líà ni! Ó sì wí fún Lábánì pé, Èwo ni iwọ́ ṣe sí mi yìí Ṣe bí nítorí Rákélì ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ́ tàn mi Lábánì sì dáhùn pé, Kò bá àṣà wa mu láti fi àbúrò fún ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Mú sùúrù parí ọ̀sẹ̀ ìgbéyàwó yìí ná, nígbà náà ni èmi yóò fi àbúrò rẹ̀ fún ọ pẹ̀lú, bí ìwọ ó bá ṣiṣẹ́ sìn mi fún ọdún méje mìíràn Jákọ́bù sì gbà láti sin Lábánì fún ọdún méje mìíràn Lábánì sì fi Rákélì ọmọ rẹ̀ fún un bí aya Lábánì sì fi Bílíhà ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Rákélì bí ìránṣẹ́ Jákọ́bù sì bá Rákélì náà lòpọ̀ Ó sì fẹ́ràn Rákélì ju Líà lọ, ó sì ṣiṣẹ́ sin Lábánì fún ọdún méje mìíràn Nígbà tí Ọlọ́run sì ri pé, Jákọ́bù kò fẹ́ràn Líà, ó sí i ni inú ṣùgbọ́n Rákélì yàgàn Líà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rúbẹ́nì, nítorí ó wí pé, Nítorí Ọlọ́run ti mọ ìpọ́njú mi, dájúdájú, ọkọ mi yóò fẹ́ràn mi báyìí Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Símónì, wí pé Nítorí tí Olúwa ti gbọ́ pé a kò fẹ́ràn mi, ó sì fi èyí fún mi pẹ̀lú Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì wí pé, Nigbà yìí ni ọkọ mi yóò fara mọ́ mi, nítorí tí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un, nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Léfì Ó sì tún lóyún, ó sì tún jẹ́ pé ọmọkùnrin ni ó bí, ó sì wí pé, Nígbà yìí ni èmi yóò yin Olúwa Ó sì pe orukọ rẹ̀ ní Júdà Ó sì dáwọ́ ọmọ bíbí dúró Ìṣubú Ènìyàn Ejò ṣáà ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yóòkù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ Ó sọ fún obìnrin náà pé, Ǹjẹ́ òtítọ́ há ni Ọlọ́run wí pé, Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èṣo èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà Obìnrin náà dá ejò lóhùn pé, Àwá lè jẹ lára àwọn èṣo igi tí ó wà nínú ọgbà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ pé, Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ lára èṣo igi tí ó wà láàrin ọgbà, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ kàn án, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò kú   Ejò wí fún obìnrin náà pé, Ẹ̀yin kì yóò kú ikúkíkú kan Nítorí Ọlọ́run mọ̀ wí pé, bí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, ojú yín yóò là, ẹ̀yin yóò sì dàbí Ọlọ́run, ẹ̀yin yóò sì mọ rere yàtọ̀ sí búburú Nígbà tí obìnrin náà rí i wí pé èṣo igi náà dára fún oúnjẹ àti pé, ó sì dùn ún wò, àti pé ó ń mú ni ní ọgbọ́n, ó mú díẹ̀ níbẹ̀, ó sì jẹ ẹ́ Ó sì mú díẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́ Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòòhò wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró Olúwa Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú Olúwa Ọlọ́run sí àárin àwọn igi inú ọgbà Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, Níbo ni ìwọ wà Ó dáhùn pé, Mo gbúrò ó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí nítorí pé, mo wà ní ìhòòhò, mo sì fi ara pamọ́ Ọlọ́run wí pé, Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòòhò ni ìwọ wà Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èṣo igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni Ọkùnrin náà wí pé, Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èṣo igi náà, mo sì jẹ ẹ́ Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí Obìnrin náà dáhùn pé, Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́ Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí, Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn àti gbogbo ẹran igbó tó kù lọ! Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́, ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárin ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú ọmọ rẹ àti irú ọmọ obìnrin náà òun yóò fọ́ orí rẹ ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀ Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí, òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ Ọlọ́rún sì wí fún Ádámù pé, Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èṣo igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀, Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èsùsú fún ọ, ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ Nínú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò máa jẹun títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá erùpẹ̀ ilẹ̀ ṣáà ni ìwọ, ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀ Ádámù sì sọ aya rẹ̀ ní Éfà nítorí òun ni yóò di ìyá gbogbo alààyè Olúwa sì dá ẹ̀wù awọ fún Ádámù àti aya rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n Olúwa Ọlọ́run sì wí pé, Ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan lára wa, ó mọ rere àti búburú A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó mú lára èṣo igi ìyè kí ó sì jẹ, kí ó sì wà láàyè títí láéláé Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run lé e kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì láti lọ máa ro ilẹ̀ nínú èyí tí a ti mú un jáde wá Lẹ́yìn tí ó ti lé ènìyàn jáde tan, ó fi àwọn Kérúbù àti idà iná tí ó ń kọ mọ̀nàmọ̀nà ṣíwájú àti sẹ́yìn, sọ́ ọ̀nà tí ó lọ síbi igi ìyè, ní ìhà ìlà oòrún ọgbà Édẹ́nì Agbo Ẹran Jákọ́bù Pọ̀ Sí i Nígbà tí Rákélì rí i pe òun kò bímọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara sí Líà, arabìnrin rẹ̀, ó sì wí fún Jákọ́bù pé, Fún mi lọmọ, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó kú Inú sì bí Jákọ́bù sí i, ó sì wí pé, Èmi ha wà ní ipò Olúwa , ẹni tí ó mú ọ yàgàn bí Nígbà náà ni Rákélì wí pé, Bílíhà ìránṣẹ́bìnrin mi nìyìí, bá a lòpọ̀, kí ó ba à le bí ọmọ fún mi, kí èmi si le è tipaṣẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ Báyìí ni Rákélì fi Bílíhà fún Jákọ́bù ní aya, ó sì bá a lò pọ̀ Bílíhà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Jákọ́bù Rákélì sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe ìdájọ́ mi ó sì ti gbọ́ ohún ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ni ọmọkùnrin kan Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì Bílíhà, ọmọ ọ̀dọ̀ Rákélì sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kéjì fún Jákọ́bù Nígbà náà ni Rákélì wí pé, Mo ti bá ẹ̀gbọ́n mi ja ìjàkadì ńlá, èmi sì ti borí Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Náfítalì Nígbà tí Líà sì ri pé òun ko tún lóyún mọ́, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, Ṣílípà fún Jákọ́bù bí aya Ṣílípà ọmọ ọ̀dọ̀ Líà sì bí ọmọkùnrin kan fún Jákọ́bù Nígbà náà ni Líà wí pé, Orí rere ni èyi! Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Gádì Ṣílípà ọmọ ọ̀dọ̀ Líà sì tún bí ọmọkùnrin kejì Nígbà náà ni Líà wí pé, Mo ní ayọ̀ gidigidi! Àwọn ọmọbìnrin yóò sì máa pe mí ní Alábùkún fún Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Áṣérì Ní ọjọ́ kan, ní àkókò ìkórè ọkà jéró, Rúbẹ́nì jáde lọ sí oko, ó sì rí ọ̀gbòn mádírákì, ó sì mu un tọ Líà ìyá rẹ̀ wá Rákélì sì wí fún Líà pé, Jọ̀wọ́ fún mi ní ara mádírákì tí ọmọ rẹ mú wá Ṣùgbọ́n Líà da lóhùn pé, Ọkọ mi tí o gbà kò tó kọ́ Ṣe ìwọ yóò tún gba mádírákì ọmọ mi pẹ̀lú Rákélì sì dáhùn pé, Ó dára, yóò sùn tì ọ́ lálẹ́ yìí nítorí mádírákì ọmọ rẹ Nítorí náà, nígbà tí Jákọ́bù ti oko dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, Líà jáde lọ pàde rẹ̀, ó sì wí pé, O ní láti sun ọ̀dọ̀ mi ní alẹ́ yìí nítorí mo ti fi mánídárákì tí ọmọ mi wá bẹ̀ ọ́ lọ́wẹ̀ Nítorí náà ni Jákọ́bù sùn tì í ní alẹ́ ọjọ́ náà Ọlọ́run sì gbọ́ tí Líà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kárùn-un fún Jákọ́bù Nígbà náà ni Líà wí pé, Ọlọ́run ti ṣẹ̀san ọmọ ọ̀dọ̀ mi ti mo fi fún ọkọ mi fún mi, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákárì Líà sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jákọ́bù Nígbà náà ni Líà tún wí pé Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn iyebíye, nígbà yìí ni ọkọ mi yóò máa bu ọlá fún mi Nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ni Ṣébúlúnì Lẹ́yìn èyí, ó sì bí ọmọbìnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dínà Nígbà náà ni Ọlọ́run rántí Rákélì, Ọlọ́run sì gbọ́ tirẹ̀, ó sì sí i ní inú Ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan ó sì wí pé, Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn mi kúrò Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ni Jóṣẹ́fù, ó sì wí pé, Ǹjẹ́ kí Olúwa kí ó fi ọmọkùnrin mìíràn kún-un fún mi Lẹ́yìn tí Rákélì ti bí Jóṣẹ́fù, Jákọ́bù wí fún Lábánì pé, Jẹ́ kí èmi máa lọ sí ilẹ̀ mi tí mo ti wá Kó àwọn ọmọ àti ìyàwó mi fún mi, àwọn ẹni tí mo ti torí wọn sìn ọ́ Ki èmi lè máa bá ọ̀na mi lọ O sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ tó Ṣùgbọ́n Lábánì wí fún un pé, Bí o bá ṣe pé mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ dúró, nítorí, mo ti ṣe àyẹ̀wò rẹ, mo sì rí i pé Olúwa bùkún mi nítorí rẹ Sọ ohun tí o fẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ, èmi yóò sì san án Jákọ́bù sì wí fún un pé, Ìwọ sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ àti bí ẹran ọ̀sìn rẹ ti pọ̀ si lábẹ́ ìtọ́jú mi Ìwọ̀nba díẹ̀ sá à ni o ní kí èmi tó dé, ó sì ti pọ̀ sí i gidigidi, Olúwa sì ti bùkún ọ nínú gbogbo èyí tí mo ṣe Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà wo ní èmi yóò pèsè fún ìdílé tèmi Ó sì tún béèrè wí pé, Kín ni kí èmi ó fi fún ọ Jákọ́bù dáhùn pé, Má fun mi ni ohunkóhun, ṣùgbọ́n bí ìwọ yóò bá ṣe ohun tí mo fẹ́ sọ yìí, èmi yóò sì máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ, èmi yóò sì máa bọ́ wọn Jẹ́ kí èmi kí ó la agbo ẹran kọjá ní òní, èmi yóò sì mú gbogbo àgùntàn onílà àti èyí tí ó ní àmì, àti gbogbo àgbò dúdú pẹ̀lú ewúrẹ́ onílà tàbí tí ó ní àmì Àwọn wọ̀nyí ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ mi Òtítọ́ inú mi yóò sì jẹ́rìí fún mi ní ọjọ́ iwájú nígbà tí ìwọ bá wo owó-iṣẹ́ mi tí ìwọ san fún mi, yóò sì ṣe pé gbogbo èyí tí kì í bá ṣe onílà tàbí alámì nínú ewúrẹ́ tàbí tí kì í ṣe dúdú nínú àgùntàn, tí o bá rí ni ọ̀dọ̀ mi ni kí o kà sí mi lọ́rùn pé jíjí ni mo jí i gbé Lábánì sì dáhùn pé, Mo faramọ́ ọn, ṣe bí ìwọ ti wí Ní ọjọ́ náà gan-an ni Lábánì kó gbogbo ewúrẹ̀ tí ó lámì tàbí ilà , pẹ̀lú gbogbo àgbò dúdú, ó sì fi wọ́n sí ìtọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀ Ibi tí Lábánì àti Jákọ́bù sì wà sí ara wọn, sì tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta Jákọ́bù sì ń tọ́jú agbo ẹran Lábánì tí ó kù Nígbà náà ni Jákọ́bù gé ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́ tútù kan lára igi pópílárì, àti álímọ́ńdì àti igi Píléénì Ó sì bó èèpo kúrò ní ibi kọ̀ọ̀kan lára igi náà láti fún igi náà ní àwọ̀ ju ẹyọ kan lọ Ó sì mú àwọn ọ̀pá wọ̀nyí tì sí ọ̀ọ́kán agbada omi níbi tí àwọn ẹran ti lè rí i nígbà tí wọ́n bá wá mu omi Tí àwọn ẹran sì ń gùn, níwájú àwọn ọ̀pá náà, wọn sì bí àwọn ẹran onílà àti alámì, àwọn tí ó ní tótòtó lára Nígbà náà ni ó ya àwọn abo ẹran kúrò nínú agbo ẹran Lábánì, ó sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àgbò, ó sì mú kí wọn máa gùn pẹ̀lú àwọn àgbò Jákọ́bù dúdú nìkan, bẹ́ẹ̀ ni ó kó agbo-ẹran jọ fún ara rẹ̀ láti ara agbo ẹran Lábánì Nígbà kígbà tí àwọn ẹran tí ó lera bá ń gùn, Jákọ́bù yóò fi àwọn ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú wọn, ní ibi tí wọn ti ń mumi Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ wí pé wọn kò lera, kò ní fi àwọn ọ̀pá náà lélẹ̀ Nítorí náà, àwọn tí kò lera ń jẹ́ ti Lábánì, nígbà tí àwọn tí ó lera ń jẹ́ ti Jákọ́bù Nítorí ìdí èyí, Jákọ́bù di ọlọ́rọ̀ gidigidi, agbo-ẹran rẹ̀ pọ̀ àti àwọn ìránṣẹ́-kùnrin, ìránṣẹ́-bìnrin pẹ̀lú ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Jákọ́bù Ṣá kúrò lọ́dọ̀ Lábánì Jákọ́bù sì gbọ́ pé àwọn ọmọ Lábánì ń wí pé, Jákọ́bù ti gba gbogbo ohun ìní baba wa, ó sì ti kó ọrọ̀ jọ fún ara rẹ̀ lára àwọn ohun tí í ṣe ti baba wa Jákọ́bù sì ṣàkíyèsí pé ìwà Lábánì sí òun ti yí padà sí ti àtẹ̀yìnwá Nígbà náà ni Olúwa wí fún Jákọ́bù pé, Padà lọ sí ilẹ̀ àwọn baba à rẹ, sí ọ̀dọ̀ àwọn ará rẹ, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ Jákọ́bù sì ránṣẹ́ pe Rákélì àti Líà sí pápá níbi tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ wà Ó sì wí fún wọn pé, Mo rí i wí pé ìwà baba yín sí mi ti yí padà sí ti tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run baba mi wà pẹ̀lú mi Ẹ sáà mọ̀ pé, mo ti fi gbogbo agbára mi ṣiṣẹ́ fún baba yín, Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ baba yín ti rẹ́ mi jẹ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó sì ti yí owó iṣẹ́ mi padà Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò jẹ́ kí ó le è pa mi lára Tí ó bá wí pé, Àwọn ẹran onílà ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ, nígbà náà ni gbogbo àwọn ẹran ń bí onílà bí ó bá sì wí pé, Àwọn ẹran oni-tótòtó ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ nígbà náà ni gbogbo ẹran ń bi oní-tótòtó Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run gba ẹran baba yín, ó sì fi fún mi Ní àsìkò tí àwọn ẹran ń gùn, mo la àlá mo sì ri pé àwọn òbúkọ tí wọ́n ń gun àwọn ẹran jẹ́ oní-tótòtó, onílà àti alámì Ańgẹ́lì Ọlọ́run wí fún mi nínú àlá náà pé, Jákọ́bù, mo sì wí pé, Èmi nìyí Ó sì wí pé, Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wò ó, gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran jẹ́ oni tótòtó, onílà àti alámì, nítorí mo ti rí gbogbo ohun ti Lábánì ń ṣe sí ọ Èmi ni Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì, níbi tí ìwọ ti ta òróró sí òpó , ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti sìn mi Nísinsin yìí, kúrò ní ilẹ̀ yìí kíákíá kí o sì padà sí ilẹ̀ ibi tí a gbé ti bí ọ   Nígbà náà ni Rákélì àti Líà dàhún pé, Ìpín wo ní nínú ogún baba wa Àjèjì ha kọ́ ni ó kà wá sí Kì í ṣe pé torí pé ó tà wá nìkan, ṣùgbọ́n ó ti ná gbogbo owó tí ó gbà lórí wa tán Dájúdájú gbogbo ọrọ̀ ti Ọlọ́run gbà lọ́wọ́ baba wa fún ọ, tiwa àti ti àwọn ọmọ wa ní í ṣe Nítorí náà ohun gbogbo tí Ọlọ́run bá páṣẹ fun ọ láti ṣe ni kí ìwọ kí ó ṣe Nígbà náà ni Jákọ́bù gbé àwọn ọmọ àti aya rẹ̀ gun ràkunmí Ó sì da gbogbo agbo ẹran rẹ̀ ṣáájú pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tí ó ti kó jọ ni Padani-Árámù, láti lọ sí ọ̀dọ̀ Ísáákì baba rẹ̀ ni ilẹ̀ Kénánì Nígbà tí Lábánì sì lọ láti rẹ́run àgùntàn, Rákélì sì jí àwọn ère òrìṣà ilé baba rẹ̀ Síwájú sí i, Jákọ́bù tan Lábánì ará Árámù, nítorí kò sọ fún un wí pé òun ń sá lọ Ó sì sá lọ pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ni, ó sì la odò kọjá , ó sì kọrí sí àwọn ilẹ̀ olókè ti Gílíádì Ní ọjọ́ kẹ́ta ni Lábánì gbọ́ pé Jákọ́bù ti sa lọ Ó sì mú àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì lépa Jákọ́bù, ó sì lépa wọn fún ọjọ́ méje, ó sì bá wọn ní òkè Gílíádì Ọlọ́run sì yọ sí Lábánì ará Arámáínì lójú àlá ní òru, ó sì wí fun un pé, Ṣọ́ra, má ṣe sọ ohunkóhun fún Jákọ́bù, ìbá à ṣe rere tàbí búburú Jákọ́bù ti pa àgọ́ rẹ̀ si orí òkè kan, nígbà tí Lábánì bá a Lábánì àti àwọn tí ó wá pẹ̀lú rẹ̀ sì pàgọ́ tiwọn sí ilẹ̀ òkè Gílíádì Nígbà náà ni Lábánì wí fún Jákọ́bù pé, Èwo ni ìwọ ṣe yìí Tí ìwọ sì tàn mi, ó sì kó àwọn ọmọbìnrin mi bi ìgbékùn tí a mú lógun Èéṣe tí ìwọ yọ́ lọ tí ìwọ sì tàn mi Kín ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé ìwọ ń lọ, kí èmi fi ayọ̀ sìn ọ, pẹ̀lú orin àti ohun èlò orin Ìwọ kò tilẹ̀ jẹ́ kí èmi fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ mi lẹ́nu, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi pé ó dìgbà Ohun tí ìwọ ṣe yìí jẹ́ ìwà òmùgọ Mo ní agbára láti ṣe ọ ni ibi, ṣùgbọ́n ní òru àná, Ọlọ́run baba rẹ sọ fún mi pé, kí èmi ṣọ́ra, kí èmi má ṣe sọ ohun kan fún ọ, ìbáà ṣe rere tàbí búburú Nísin yìí, ìwọ ti lọ nítorí ìwọ fẹ́ lati padà lọ sí ilé baba rẹ, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìwọ fi jí àwọn òrìṣà mi Jákọ́bù dá Lábánì lóhùn pé, Ẹ̀rù ni ó bà mi nítorí, mo rò pé ìwọ le fi tipá tipá gba àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́ mi Ṣùgbọ́n bí o bá ri ẹnikẹ́ni pẹ̀lú ère rẹ, kí ẹni náà di òkú Ó tún wí pé, Níwájú gbogbo ìbátan wa báyìí, wò ó fúnra rẹ, bí o bá rí ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ, mú un Jákọ́bù kò sì mọ̀ pé, Rákélì ni ó jí àwọn òrìṣà náà Lábánì sì lọ sínú àgọ́ Jákọ́bù àti ti Líà àti ti àwọn ìránṣẹ́-bìnrin méjèèjì, kò sì rí ohunkóhun Lẹ́yìn ìgbà tí ó jáde nínú àgọ́ Líà ni ó lọ sí àgọ́ Rákélì Rákélì sì gbé àwọn òrìṣà náà sínú gàárì ràkunmí, ó sì jókòó lé e lórí Lábánì sì wá gbogbo inú àgọ́, kò sì rí ohunkóhun Rákélì sì wí fún baba rẹ̀ pé, Má ṣe bínú pé èmi ò le dìde dúró níwájú rẹ bàbá à mi, ohun tí ó fà á ni pé, mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́ Ó sì wá àgọ́ kiri, kò sì rí àwọn òrìṣà-ìdílé náà Inú sì bí Jákọ́bù, ó sì pe Lábánì ní ìjà pé, Kín ni ẹ̀ṣẹ̀ mi Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ tí ìwọ fi ń lépa mi bí ọ̀daràn Nísinsin yìí tí ìwọ ti tú gbogbo ẹrù mi wò, kín ni ohun tí í ṣe tirẹ̀ tí ìwọ rí Kó wọn kalẹ̀ báyìí níwájú gbogbo ìbátan rẹ àti tèmi, kí wọn kí ó sì ṣe ìdájọ́ láàrin àwa méjèèjì Mo ti wà lọ́dọ̀ rẹ fún ogún ọdún, àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rẹ kò sọnù bẹ́ẹ̀ n kò pa ọ̀kan jẹ rí nínú àwọn àgbò rẹ Èmi kò mú ọ̀kankan wá fún ọ rí nínú èyí tí ẹranko búburú fà ya, èmi ni ó fara mọ́ irú àdánù bẹ́ẹ̀ Ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá sì jí lọ, lọ́sàn án tàbí lóru, ìwọ ń gba owó rẹ̀ lọ́wọ́ mi Báyìí ni mo wà oòrùn ń pa mi lọ́sàn-án, òtútù ń pa mi lóru, mo sì ń ṣe àìsùn Báyìí ni ohun gbogbo rí fún ogún ọdún tí mo fi wà nínú ilé rẹ Ọdún mẹ́rìnlá ni mo fi sìn ọ́ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì, mo sì sìn ọ fún ọdún mẹ́fà fún àwọn ẹran ọ̀sìn, lẹ́ẹ̀mẹ́wàá ni o sì yí owó iṣẹ́ mi padà Bí ó bá ṣe pé Ọlọ́run àwọn baba mi, Ọlọ́run Ábúráhámù àti ẹ̀rù Ísáákì kò wà pẹ̀lú mi ni, ìwọ ì bá ti lé mi jáde lọ́wọ́ òfo Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ti rí gbogbo ìpọ́njú mi àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ mi ṣe, ó sì kìlọ̀ fún ọ lóru àná Lábánì sì dá Jákọ́bù lóhùn, Tèmi ni àwọn obìnrin wọ̀nyí, ọmọ mi ni àwọn ọmọ wọ̀nyí pẹ̀lú, àwọn agbo ẹran yìí, tèmi ni wọ́n pẹ̀lú Gbogbo ohun tí o rí wọ̀nyí, tèmi ni Kín ni mo wá le ṣe sí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí àti àwọn ọmọ wọn tí wọn bí Wá, jẹ́ kí a dá májẹ̀mú pẹ̀lú ara wa, èyí yóò sì jẹ́ ẹ̀rí ní àárin wa Jákọ́bù sì mú òkúta kan ó sì gbé e dúró bí ọ̀wọ̀n Ó sì wí fún àwọn ìbátan rẹ̀ pé, Ẹ kó àwọn òkúta díẹ̀ jọ Wọ́n sì kó òkúta náà jọ bí òkítì wọ́n sì jẹun níbẹ̀ Lábánì sì pe orúkọ rẹ̀ ní Akojọ òkítì ẹ̀rí, ṣùgbọ́n Jákọ́bù pè é ni Gálíídì Lábánì sì wí pé, Òkítì yìí jẹ́ ẹ̀rí láàrin èmi àti ìwọ ní òní Ìdí nìyí tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ni Gálíídì Ó tún pè é ni Mísípà nítorí, ó wí pé, Kí Olúwa kí ó máa sọ́ èmi àti ìwọ nígbà tí a bá yà kúrò lọ́dọ̀ ara wa tán Bí o bá fìyà jẹ àwọn ọmọbìnrin mi, tàbí tí o fẹ́ aya mìíràn yàtọ̀ sí wọn, rántí pé, Ọlọ́run ń bẹ láàrin wa bí ẹlẹ́rìí bí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ sí Lábánì tún sọ síwájú pé, Òkítì àti òpó tí mo gbé kalẹ̀ láàrin èmi àti ìwọ yìí, yóò jẹ́ ẹ̀rí wí pé èmi kò ni ré òpó àti òkítì yìí kọjá láti bá ọ jà àti pé ìwọ pẹ̀lú kì yóò kọjá òkítì tàbí òpó yìí láti ṣe mí ní ibi Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Náhórì, àti Ọlọ́run baba wọn ṣe ìdájọ́ láàrin wa Báyìí ni Jákọ́bù dá májẹ̀mu ní orúkọ Ọlọ́run Ẹ̀rù-Ísáákì baba rẹ̀ Jákọ́bù sì rúbọ níbẹ̀ ni orí òkè, ó sì pe àwọn ẹbí rẹ̀ láti jẹun Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹun, ibẹ̀ náà ni wọ́n sùn ní ọjọ́ náà Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Lábánì fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì súre fún wọn Lábánì sì padà lọ sí ilé Jákọ́bù Gbáradì Láti Pàdé Éṣáù Jákọ́bù sì ń bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀ Nígbà tí Jákọ́bù rí wọn, ó wí pé, Àgọ́ Ọlọ́run nìyi! Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ni Máhánáímù Jákọ́bù sì rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú ara rẹ̀ sí Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀ ni ilẹ̀ Ṣéírì ní orílẹ̀-èdè Édómù Ó pàṣẹ fún wọn pé, Èyí ni ẹ̀yin yóò wí fún Ísọ̀ olúwa mi, Jákọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, Mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Lábánì títí ó fi di àṣìkò yìí Mo ní màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn àti ewúrẹ́ Mo tún ni àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin Mo ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi kí èmi le è rí ojúrere rẹ   Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà padà tọ Jákọ́bù wà, wọ́n wí pé Ísọ̀ arákùnrin rẹ ti múra láti wá pàdé rẹ pẹ̀lú irinwó ọkùnrin Pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìbànújẹ́ ni Jákọ́bù fi pín àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìpín méjì, ó sì pín àwọn ẹran ọ̀sìn, agbo ẹran àti ràkúnmí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Nítorí ó rò ó nínú rẹ̀ pé, Bí Ísọ̀ bá kọjú ogun sí ìpín kan, ìpín kejì yóò sá àsálà Nígbà náà ni Jákọ́bù gbàdúrà pe, Ọlọ́run Ábúráhámù baba mi, àti Ọlọ́run Ísáákì baba mi, Olúwa tí ó wí fún mi pé, Padà sí orílẹ̀-èdè rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, Èmi yóò sì ṣe ọ́ ní rere, Èmi kò tilẹ̀ yẹ fún àánú àti òtítọ́ tí o ń fi hàn fún ìránṣẹ́ rẹ Nítorí pé, kìkì ọ̀pá mi ni mo mu kúrò ni ilé kọjá Jọ́dánì yìí, ṣùgbọ́n nísin yìí, èmi ti di ẹgbẹ́ méjì Jọ̀wọ́ Olúwa gbà mí lọ́wọ́ Ísọ̀ arákùnrin mi, nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé yóò wá dojú ìjà kọ mí àti àwọn ìyàwó pẹ̀lú àwọn ọmọ mi Ṣùgbọ́n ìwọ ti ṣèlérí pé, Èmi yóò mú ọ gbilẹ̀, èmi yóò sì mú kí àwọn ìran rẹ dà bì í yanrìn òkun tí ẹnikẹ́ni kò le è kà   Ó sì lo òru ọjọ́ náà níbẹ̀ Ó mú ẹ̀bùn fún arákùnrin rẹ̀ nínú ohun ìní rẹ̀ Igba ewúrẹ́ , ogún òbúkọ, igba àgùntàn, ogún àgbò, Ọgbọ̀n abo ràkunmí pẹ̀lú ọmọ wọn, ogójì abo màlúù àti akọ màlúù mẹ́wàá , ogún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá Ó sì fi wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrin ọ̀wọ́ agbo ẹran kọ̀ọ̀kan sí èkeji Ó pàṣẹ fún èyí tí ó ṣáájú pé, Nígbà tí arákùnrin mi Ísọ̀ bá pàdé rẹ tí ó sì béèrè ẹni tí ìwọ í ṣe àti ibi tí ìwọ ń lọ àti ẹni tí ó ni agbo ẹran tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ, Nígbà náà ni ìwọ yóò wí pé, Ti ìránṣẹ́ rẹ Jákọ́bù ni wọ́n Ẹ̀bùn ni ó sì fi wọ́n ṣe fún Ísọ̀ olúwa mi, òun pàápàá ń bọ̀ lẹ́yìn wa   Jákọ́bù sì pàṣẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún ọ̀wọ́ kejì àti ẹ̀kẹta àti àwọn tókù tí ó tẹ̀lé agbo ẹran pé, Ohun kan ṣoṣo yìí náà ni kí ẹ sọ fún Ísọ̀ nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀ Kí ẹ rí i dájú wí pé, ẹ sọ fún-un pé, Jákọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ lẹ́yìn wa   Èrò Jákọ́bù ni láti fi àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tu Ísọ̀ lójú pé bóyá inú Ísọ̀ yóò dùn sí òun nígbà tí àwọn bá pàdé Nítorí náà ẹ̀bùn Jákọ́bù ṣáájú rẹ̀ lọ, Jákọ́bù pàápàá sì lo òru ọjọ́ náà nínú àgọ́ Ó sì dìde ní òru ọjọ́ náà, ó mú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ méjèèjì, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kọ̀ọ̀kànlá, wọ́n sì kọjá ní ìwọdò Jábókù Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rán wọn kọjá odò tán sí òkè-odò, ó sì rán àwọn ohun-ìní rẹ̀ kọjá pẹ̀lú Ó sì ku Jákọ́bù nìkan, ọkùnrin kan sì báa ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́jú Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jákọ́bù, ó fọwọ́ kan-án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ìké, bí ó ti ń ja ìjàkadì Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́ Ṣùgbọ́n Jákọ́bù dá a lóhùn pé, Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀ Ó sì wí fún un pé, Jákọ́bù ni òun ń jẹ́ Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jákọ́bù mọ́ bí kò ṣe Ísírẹ́lì, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí Jákọ́bù sì bẹ ọkùnrin náà pé, Sọ orúkọ rẹ fún mi Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà ṣáà dáhùn pé, Èéṣe tí o n béèrè orúkọ mi Lẹ́yìn náà ó ṣúre fún Jákọ́bù níbẹ̀ Jákọ́bù sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Pẹ́núẹ́lì pé, Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, ṣíbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí Bí ó sì ti ń kọjá Pẹ́núẹ́lì, oòrùn ràn bá a, ó sì ń tiro nítorí itan rẹ̀ Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í fií jẹ iṣan tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀ títí di òní-olónìí, nítorí níbi iṣan náà ni a ti fọwọ́ kan ibi tí egungun itan Jákọ́bù ti bẹ̀rẹ̀ Jákọ́bù àti Ísọ̀ Pàdé Jákọ́bù sì gbójú sókè, ó sì rí Ísọ̀ àti irinwó ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún Líà, Rákélì àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì Ó sì ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn ṣíwájú, Líà àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọ̀wọ́ kejì tí ó tẹ̀lé wọn, Rákélì àti Jóṣẹ́fù sì wà lẹ́yìn pátapáta Jákọ́bù fúnra rẹ̀ wa lọ ṣíwájú pátapáta, ó sì tẹríba ní ìgbà méje bí ó ti ń sún mọ́ Ísọ̀, arákùnrin rẹ̀ Ṣùgbọ́n Ísọ̀ sáré pàdé Jákọ́bù, ó sì dì mọ́ ọn, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì fẹnu kò ó lẹ́nu Àwọn méjèèjì sì sunkún Nígbà tí Ísọ̀ sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jákọ́bù, ó bèèrè lọ́wọ́ Jákọ́bù pé, Ti tani àwọn wọ̀nyí Jákọ́bù sì fèsì wí pé, Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn súnmọ́ tòsí, wọ́n sì tẹríba Lẹ́yìn náà ni Líà àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú dé, wọ́n sì tún tẹríba Ní ìkẹyìn ni Jósẹ́fù àti Rákélì dé, wọ́n sì tún tẹríba pẹ̀lú Ísọ̀ sì béèrè pé, Kín ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ̀ tí mo pàdé wọ̀nyí Jákọ́bù dáhùn pé, Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi Ṣùgbọ́n Ísọ̀ wí pé, Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ Jákọ́bù bẹ̀ ẹ́ wí pé, Rárá bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ṣe pé, mo rí ojú rere rẹ, jọ̀wọ́ gba wọ́n lọ́wọ́ mi Bí mo ṣe rí ojú rẹ̀ yìí, ó dàbí wí pé mo rí ojú Ọlọ́run ni báyìí, tí inú un rẹ̀ ti dùn sí mi Jọ̀wọ́ gba àwọn ohun tí mo mú wá wọ̀nyí lọ́wọ́ mi Nítorí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ hàn sí mi, gbogbo ohun tí mo fẹ́ sì ni mo ní Nígbà tí Jákọ́bù sì rọ̀ ọ́ pé Ísọ̀ gbọdọ̀ gbà wọ́n, Ísọ̀ sì gbà á Nígbà náà ni Ísọ̀ wí pé, Jẹ́ kí a máa lọ, n ó sìn ọ Ṣùgbọ́n Jákọ́bù wí fún un pé, Ṣe ìwọ náà ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ wọ̀nyí kéré, àwọn màlúù àti àgùntàn pẹ̀lú sì ní àwọn ọmọ kéékèèké Bí a bá dà wọ́n rìn jìnnà ju bí agbára wọn se mọ lọ, wọ́n lè kú Èmi bẹ̀ ọ́, máa lọ ṣíwájú ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ó sì máa rọra bọ̀, títí èmi àti àwọn ọmọ yóò fi dé ọdọ̀ olúwa mi ní Ṣéírì Ísọ̀ wí pé, Jẹ́ kí n fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ nínú àwọn ọkùnrin mi nígbà náà Jákọ́bù wí pé, Èéṣe, àní kí n sáà rí ojú rere olúwa mi Ní ọjọ́ náà gan-an ni Ísọ̀ padà lọ sí Ṣéírì Jákọ́bù sì lọ sí Ṣúkótù, ó sì kọ́ ilé fún ara rẹ̀, ó sì ṣe ọgbà fún àwọn ẹran Ìdí èyí ní a fi ń pe ibẹ̀ ní Ṣúkótù Lẹ́yìn ìgbà tí Jákọ́bù tí Padani-Árámù dé Àlàáfíà ni Jákọ́bù dé ìlú Sẹ́kẹ́mù ní ilẹ̀ Kénánì, ó sì pàgọ́ sí ìtòòsí ìlú náà Ó sì ra ilẹ̀ kan tí ó pàgọ́ sí ni ọgọ́rùn-ún owó fàdákà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì tíí ṣe bàbá Sẹ́kẹ́mù Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan tí ó pè ní El Elohe Ísírẹ́lì Dínà àti Àwọn Ará Ṣékémù Ní ọjọ́ kan, Dínà ọmọbìnrin tí Líà bí fún Jákọ́bù jáde lọ bẹ àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà wò Nígbà tí Ṣékémù ọmọ ọba Hámórì ará Hífì rí i, ó mú un, ó sì fi ipá bá a lo pọ̀ Ọkàn rẹ sì fà sí Dínà ọmọ Jákọ́bù gan-an, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ó sì bá ọmọbìnrin náà sọ̀rọ̀-ìfẹ́ Ṣékémù sì wí fún Hámórì bàbá rẹ̀ pé, Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi bí aya Nígbà tí Jákọ́bù gbọ́ ohun tí ó sẹlẹ̀ pé a fi ipá bá Dínà ọmọbìnrin òun lò pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ wà nínú pápá níbi tí wọ́n ti ń daran nítorí náà ó mú sùúrù títí tí wọ́n fi dé Ámórì baba Ṣékémù sì jáde wá láti bá Jákọ́bù sọ̀rọ̀ Àwọn ọmọ Jákọ́bù sì ti oko dé, wọ́n sì gbọ́ ohun tí ó ṣelẹ̀ inú wọn sì bàjẹ́, ó sì ń bí wọn nínú gidigidi, nítorí pé, ohun àbùkù ńlá ni ó jẹ́ pé Ṣékémù bá ọmọ Jákọ́bù lò pọ̀-irú ohun tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá Hámórì sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé, Ọkàn ọmọ mi Ṣékémù fà sí ọmọ rẹ Jọ̀wọ́ fi fún un gẹ́gẹ́ bí aya Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbéyàwó láàrin ara wa, kí àwọn ọmọ yín kó máa fẹ́ àwọn ọmọ wa Ẹ lè máa gbé láàrin wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrin wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín Ṣékémù sì wí fún baba àti arákùnrin Dínà pé, Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojú rere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà Iyekíye tí owó orí rẹ̀ bá jẹ́ àti ẹ̀bùn gbogbo tí ẹ bá fẹ́, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó, èmi yóò san-án, kí ẹ sáà jẹ́ kí ń fi ọmọ náà ṣe aya Àwọn arákùnrin Dínà sì fi ẹ̀tàn dá Ṣékémù àti Ámórì bàbá rẹ̀ lóhùn nítorí tí ó ti ba ògo Dínà arábìnrin wọn jẹ́ Wọ́n wí fún wọn pé, Àwa kò le ṣe nǹkan yìí láti fi arábìnrin wa fún aláìkọlà, nítorí àbùkù ni èyí yóò jẹ́ fún wa Àwa yóò fara mọ́ ọn bí ẹ̀yin yóò bá gbà láti dàbí i tiwa, wí pé ẹ̀yin pẹ̀lú yóò kọ gbogbo ọkùnrin yín ní ilà Nígbà náà ni àwa yóò le máa fún yín ní ọmọ wa, tí àwa náà yóò máa fẹ́ ẹ yín A ó máa gbé láàrin yín, a ó sì di ara kan pẹ̀lú yín Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti kọlà, àwa yóò mú arábìnrin wa, á ó sì máa lọ Àbá náà sì dùn mọ́ Ámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀ Ọ̀dọ́mọkùnrin náà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni iyì jùlọ ní ilé bàbá rẹ̀, kò jáfara láti ṣe ohun tí wọ́n wí Nítorí tí ó fẹ́ràn ọmọbìnrin Jákọ́bù Ámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀ sì wá sí ẹnu ibodè ìlú náà wọn sì bá àwọn ará ìlú náà sọ̀rọ̀ Wí pé, Ìwa àwọn ọkùnrin wọ̀nyí dára, ẹ jẹ́ kí wọn máa gbé ní àárin wa, kí wọn sì máa ṣòwò, ilẹ̀ kúkú wà rẹpẹtẹ tó gbààyè dáradára A lè fẹ́ àwọn ọmọ wọ̀n, ki wọn sì fẹ́ tiwa pẹ̀lú Ṣùgbọ́n kin ní kan ni a lè ṣe kí wọn tó gbà láti gbé pẹ̀lú wa, ìyẹn sì ni pé àwọn ọkùnrin wa yóò kọlà bí i tiwọn Ṣe bí àwọn ẹran wọn àti ẹrú wọn àti àwọn ohun ọ̀sìn wọn ni yóò di tiwa bí a bá lè gbà bẹ́ẹ̀, wọn yóò sì máa gbé ni àárin wa Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ń jáde lẹ́nu bodè ìlú náà sì gbọ́ ti Ámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀ Gbogbo ọkùnrin ìlú náà sì kọlà Lẹ́yìn ọjọ́ kẹ́ta, nígbà tí gbogbo wọn sì wà nínú ìrora Àwọn ọmọ Jákọ́bù méjì, Símónì àti Léfì tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Dínà, sì mú idà wọn pẹ̀lú ìgboyà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin ìlú náà Wọ́n pa Ámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀, wọ́n mú Dínà kúrò ní ilé wọn, wọ́n sì jáde Àwọn ọmọ Jákọ́bù sì wọlé àwọn tí a pa, wọ́n sì kó ẹrù ìlú tí a ti ba ògo arábìnrin wọn jẹ́ Wọ́n kó màlúù wọn àti agbo ẹran wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìlú àti ní oko Gbogbo ọrọ̀ wọn, gbogbo obìnrin ìlú àti àwọn ọmọ wẹẹrẹ pátapáta ni wọ́n kó Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé wọn bí ìkógun Nígbà náà ni Jákọ́bù wí fún Símónì àti Léfì wí pé, Ẹ̀yin ti kó ìyọnu bá mi nípa sísọ mí di olóòórùn láàrin ará Kénánì àti Pérésì, tí ó ń gbé ilẹ̀ yìí Àwa kò pọ̀, bí wọn bá wá parapọ̀ sígun sí wa, gbogbo wa pátapáta ni wọn yóò parun Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, Ǹjẹ́ ó yẹ kí ó ṣe arábìnrin wa bí aṣẹ́wó Jákọ́bù Padà sí Bẹ́tẹ́lì Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Jákọ́bù pé, Gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì kí o sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀, kí o mọ pẹpẹ níbẹ̀ fún Ọlọ́run tó farahàn ọ́ nígbà tí o ń sá lọ kúrò níwájú Íṣọ̀ arákùnrin rẹ Nítorí náà, Jákọ́bù wí fún gbogbo ará ilé rẹ̀ pé, Ẹ mú gbogbo àjòjì òrìsà tí ó wà lọ́dọ̀ yín kúrò, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín Nígbà náà ni kí ẹ wá, kí ẹ jẹ́ kí a lọ sí Bẹ́tẹ́lì, níbi tí n ó ti mọ pẹpẹ fún Ọlọ́run, tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú mi tí ó sì ti ń pẹ̀lú mi níbi gbogbo tí mo ń lọ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jákọ́bù ní gbogbo àjòjì òrìsà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jákọ́bù sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sabẹ́ igi Óákù ní Ṣékémù Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò wọn Ìbẹ̀rù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì ń bá lé gbogbo ìlú tí wọ́n ń là kọjá ní ọ̀nà wọn tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹni tí ó le è dojú ìjà kọ wọ́n Jákọ́bù àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lúsì tí ó wà ní ilẹ̀ Kénánì Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Bẹ́tẹ́lì , nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn-án nígbà tí ó ń sá lọ fún arákùnrin rẹ̀ Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Dèbórà, olùtọ́jú Rèbékà kú, a sì sin-ín sábẹ́ igi Óàkù ní ìsàlẹ̀ Bẹ́tẹ́lì Nítorí náà a sọ ọ́ ní Aloni-Bákútì Lẹ́yìn tí Jákọ́bù padà dé láti Padani-Árámù, Ọlọ́run tún fara hàn-án, ó sì súre fún un Ọlọ́run sì wí fun un pé, Jákọ́bù ni orúkọ rẹ̀, a kì yóò pè ọ́ ní Jákọ́bù mọ́ bí kò ṣe Ísírẹ́lì Nítorí náà, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Ísírẹ́lì Ọlọ́run sì wí fún-un pé, Èmi ni Ọlọ́run alágbára máa bí sí i, kí o sì máa pọ̀ sí i Orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti ara rẹ̀ Gbogbo ilẹ̀ tí mo fi fún Ábúráhámù àti Ísáákì ni èmi yóò fún ọ pẹ̀lú, àti fún àwọn ìran rẹ tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn Nígbà náà ni Ọlọ́run gòkè lọ kúrò ní ibi tí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀ Jákọ́bù sì fi òkúta ṣe òpó kan sí ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ó sì ta ọrẹ ohun mímu ní orí rẹ̀, ó sì da òróró ólífì sí orí rẹ̀ pẹ̀lú Jákọ́bù sì pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì Nígbà náà ni wọ́n ń tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìn-àjò wọn láti Bẹ́tẹ́lì Nígbà tí ó sì ku díẹ̀ kí wọn dé Éfúrátì, Rákélì bẹ̀rẹ̀ sí ní rọbí, ó sì ní ìdààmú púpọ̀ Bí ó sì ti ń rọbí pẹ̀lú ìrora yìí, agbẹ̀bí wí fún-un pé Má bẹ̀rù nítorí ọmọkùnrin mìíràn ni ó ń bọ̀ yìí Bí o sì ti fẹ́ gbé ẹ̀mí mi , ó pe ọmọ rẹ̀ náà ní Bẹni-Ónì Ṣùgbọ́n Jákọ́bù sọ ọmọ náà ní Bẹ́ńjámínì Báyìí ni Rákélì kú, a sì sin-ín sí ọ̀nà Éfúrátì Jákọ́bù sì mọ òpó kan sí ibojì rẹ̀, òpó náà sì tọ́ka sí ojú ibojì Rákélì títí di òní Ísírẹ́lì sì ń bá ìrìn-àjò rẹ̀ lọ, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ sí Migida-Édérì Nígbà tí Ísírẹ́lì sì ń gbé ní ibẹ̀, Rúbẹ́nì wọlé tọ Bílíhà, àlè baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lò pọ̀, Ísírẹ́lì sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà Jákọ́bù sì bí ọmọkunrin méjìlá Àwọn ọmọ Líà Rúbẹ́nì tí í ṣe àkọ́bí Jákọ́bù, Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì àti Ṣébúlúnì Àwọn ọmọ Rákélì Jóṣẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì Àwọn ọmọ Bílíhà ìránṣẹ́bìnrin Rákélì Dánì àti Náfítalì Àwọn ọmọ Ṣílípà ìránṣẹ́-bìnrin Líà Gádì àti Áṣérì Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Jákọ́bù bí ní Padani-Árámù Jákọ́bù sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Ísáákì baba rẹ̀ ni Mámúrè ní tòsí i Kiriati-Árábà Níbi tí Ábúráhámù àti Ísáákì gbé Ẹni ọgọ́sán-an ọdún ni Ísáákì Ísáákì sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn ìpadàbọ̀ Jákọ́bù, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọjọ́-ogbó rẹ̀ Ísọ̀ àti Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ sì sin-ín Àwọn Ìránṣẹ́ Ísọ̀ Wọ̀nyí ni ìran Ísọ̀, ẹni tí a ń pè ní Édómù Nínú àwọn ọmọbìnrin Kénánì ni Ísọ̀ ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀ Ádà ọmọbìnrin Élónì ará Hítì àti Óhólíbámà, ọmọbìnrin Ánà, ọmọ ọmọ Ṣíbéónì ará Hífítì Ó sì tún fẹ́ Báṣémátì ọmọ Ísímáélì arábìnrin Nébájótù Ádà bí Élífásì fún Ísọ̀, Báṣémátì sì bí Réúẹ́lì, Óhólíbámà pẹ̀lú sì bí Jéúsì, Jálámù, àti Kórà Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Ísọ̀ bí ní Kénánì Ísọ̀ sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kénánì, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jákọ́bù arakùnrin rẹ̀ wà Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojúkan lọ Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwon méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn Báyìí ni Ísọ̀ tí a tún mọ̀ sí Édómù tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀ èdè oloke tí Ṣéírì Èyí ni ìran Ísọ̀ baba àwọn ará Édómù ní àwọn orílẹ̀ èdè olókè Ṣéírì Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Ísọ̀ Élífásì ọmọ Ádà aya Ísọ̀ àti Rúélì, ọmọ Báṣémátì tí í ṣe aya Ísọ̀ pẹ̀lú Àwọn ọmọ Élífásì ni ìwọ̀nyí Témánì, Ómárì, Ṣéfò, Gátamù, àti Kénásì Élífásì ọmọ Ísọ̀ sì tún ní àlè tí a ń pè ní Tímúnà pẹ̀lú, òun ló bí Ámálékì fún un Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ọmọ Ádà aya Ísọ̀ Àwọn ọmọ Rúélì Náhátì, Ṣérà, Ṣámà àti Mísà Àwọn ni ọmọ-ọmọ Báṣémátì aya Ísọ̀ Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Óhólíbámà ọmọbìnrin Ánà ọmọ-ọmọ Ṣíbéónì tí ó bí fún Ísọ̀ Jéúsì, Jálámì àti Kórà Wọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Ísọ̀ Àwọn ọmọ Élífásì, àkọ́bí Ísọ̀ Témánì, Ómárì, Ṣéfò, Kénásíà, Kórà, Gátamù àti Ámálékì Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Élífásì ní Édómù wá, wọ́n jẹ́ ọmọ-ọmọ Ádà Wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Rúélì, Náhátì, Ṣérátì, Ṣámò àti Mísà Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Rúélì jáde ní Édómù Ọmọ-ọmọ Básémátì aya Ísọ̀ ni wọ́n jẹ́ Àwọn ọmọ Óhólíbámà aya Ísọ̀ Jéúsì, Jálámì, àti Kórà, àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olorí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Óhólíbámà ọmọ Ánà, ìyàwó Ísọ̀ wá Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ísọ̀ Àwọn wọ̀nyí ni olórí wọn Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣéírì ara Hórì tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà Lótanì, Ṣóbálì, Ṣíbéónì, Ánà Dísónì, Éṣérì, àti Díṣánì, àwọn wọ̀nyìí ọmọ Ṣéírì ni Édómù Àwọn ọmọ Lótanì Órì àti Ómámù Arábìnrin Lótanì sì ni Tímínà Àwọn ọmọ Ṣóbálì Álífánì, Mánáhátì, Ébálì, Ṣéfò àti Onámù Àwọn ọmọ Ṣíbéónì Áíyà àti Ánà Èyí ni Ánà tí ó rí ìṣun omi gbígbóná ní inú asálẹ̀ bí ó ti ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣébéónì baba rẹ̀ Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ánà Dísónì àti Óhólíbámà Àwọn ọmọ Dísónì ni Hémídánì, Ésíbánì, Ítíránì àti Kéránì Àwọn ọmọ Éṣérì Bílíhánì, Ṣááfánì, àti Ákánì Àwọn ọmọ Díṣánì ni Húsì àti Áránì Àwọn wọ̀nyí ni olórí ìdílé Hórì Lótanì, Ṣóbálì, Ṣíbéónì, Áná, Dísónì Éṣérì, àti Díṣánì Àwọn ni olórí ìdílé àwọn ará Órì gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní ilẹ̀ Ṣéírì Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọba tí ó ti jẹ ní Édómù kí ó tó di pé a ń jẹ ọba ní Ísírẹ́lì rárá Bẹ́là ọmọ Béórì jẹ ní Édómù Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Díníhábà Nígbà tí Bẹ́là kú, Jóbábù ọmọ Ṣérà ti Bósírà sì jọba ní ipò rẹ̀ Nígbà tí Jóbábù kú, Úṣámù láti ilẹ̀ Témánì sì jọba ní ipò rẹ̀ Nígbà tí Húṣámù kú, Hádádì ọmọ Bédádì tí ó ṣẹ́gun Mídíánì ní orílẹ̀ èdè Móábù sì jọba ní ipò rẹ̀ Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Áfítì Lẹ́yìn ikú Ádádì, Ṣámílà tí ó wá láti Másírékà ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ Sámílà sì kú, Ṣáúlì ti Réhóbótì, létí odò sì jọba lẹ́yìn rẹ̀ Nígbà tí Sáúlì kú, Báálì-Hánánì ọmọ Ákíbórì jọba lẹ́yìn rẹ̀ Nígbà tí Baali-Hánánì ọmọ Ákíbórì kú, Ádádì ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Páù, Méhétà-bélì ọmọbìnrin Mátírédì àti ọmọ-ọmọ Mé-ṣáhábù ni ìyàwó rẹ̀ Àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ìjòyè tí ó ti ọ̀dọ̀ Ísọ̀ jáde wá, ní orúkọ ìdílé wọn, bí ìpínlẹ̀ wọn ti rí Tínínà, Álífánì, Jététì Ohólíbámà, Élà, Pínónì, Kénásì, Témáínì Míbísárì, Mágídíélì, àti Írámù Àwọn wọ̀nyí ni olóyè Édómù, gẹ́gẹ́ bí wọn ti tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí wọ́n gbà Èyí ni Ísọ̀ baba àwọn ará Édómù Àlá Jósẹ́fù Jákọ́bù sì gbé ilẹ̀ Kénánì ní ibi ti baba rẹ̀ ti gbé Èyí ni àwọn ìtàn Jákọ́bù Nígbà tí Jósẹ́fù di ọmọ ọdún mẹ́tadínlógún , ó ń sọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwon ọmọ Bílíhà àti Sílípà aya baba rẹ̀ Jósẹ́fù sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn Jákọ́bù sì fẹ́ràn Jósẹ́fù ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tó kù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kóríra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrin wọn Jósẹ́fù lá àlá kan, nígbà tí ó sì sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n túbọ̀ kórira rẹ̀ sí i O wí fún wọn pé Ẹ fetí sí àlá tí mo lá Sáà wò ó, àwa ń yí ìdì ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìdì ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìdì ọkà tiyín sì dòòyì yí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un Àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, Ìwọ ń gbérò àti jọba lé wa lórí bí Tàbí ìwọ ó ṣe olórí wa ní tòótọ́ Wọn sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i, nítorí àlá rẹ̀ àti nítorí ohun tí ó wí O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń forí balẹ̀ fún mi Nígbà tí ó sọ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú, baba rẹ̀ bá a wí pé, irú àlá wo ni ìwọ lá yìí Ṣé ìyá rẹ, pẹ̀lú èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ yóò wá forí bálẹ̀ níwájú rẹ ni Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń ṣe ìlara rẹ̀ ṣugbọ́n baba rẹ̀ pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ lọ́kàn rẹ̀ Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì da ẹran baba wọn lọ sí Ṣékémù Ísírẹ́lì sì wí fún Jósẹ́fù pé, Ṣé o mọ̀ pé, àwọn arákunrin rẹ ń da ẹran ní Ṣékémù, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn Jósẹ́fù sì dáhùn pé, Èmi nìyí O sì wí fún un pé, Lọ wò bí àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn agbo ẹran bá wà ní àlàáfíà, kí o sì wá jíṣẹ́ fún mi Ó sì rán Jósẹ́fù lọ láti àfonífojì Ébúrónì Nígbà tí Jósẹ́fù dé Ṣékémù, Ọkùnrin kan sì rí i tí ó ń rìn kiri inú pápá, ó sì bi í pé, Kín ni ò ń wá Ó sì dáhùn pé, Àwọn arákùnrin mi ni mò ń wá, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú agbo ẹran Ọkùnrin náà dáhùn pé, Wọ́n ti kúrò ní ìhín, mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dótanì   Jósẹ́fù sì wá àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní tòsí Dótanì Ṣùgbọ́n bí wọ́n sì ti rí i tí ń bọ̀ lókèèrè, kí ó sì tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á Alálàá ni ń bọ̀ yìí, ni wọ́n ń wí fún ara wọn Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ Nígbà tí Rúbẹ́nì gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀, Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn an, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láàyè nínú asálẹ̀ níbí Rúbẹ́nì sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀ Nítorí náà, nígbà tí Jósẹ́fù dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀— wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò Kòtò náà sì ṣófo, kò sí omi nínú un rẹ̀ Bí wọ́n sì ti jókòó láti jẹun, wọ́n gbójú sókè, wọ́n sì rí àwọn oníṣòwò ará Íṣímáélì tí wọ́n ń wọ́ bọ̀ láti Gílíádì Ràkunmí wọn sì ru tùràrí, ìkunra àti òjíá, wọ́n ń lọ sí Éjíbítì Júdà wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, Èrè kín ni ó jẹ́ bí a bá pa arákùnrin wa tí a bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ ti ọkàn wa sì ń dá wa lẹ́bi Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Íṣímáélì, kí àwa má sì pa á, ṣè bí àbúrò wa ni, ẹran ara wa àti ẹ̀jẹ̀ wa ní i ṣe Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì faramọ́ ohun tí ó sọ Nítorí náà, nigbà tí àwọn onísòwò ara Mídíánì ń kọjá, àwọn arákùnrin Jósẹ́fù fà á jáde láti inú kòtò, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Íṣímáélì ní ogún owó wúrà, wọ́n sì mú Jósẹ́fù lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì Nígbà tí Rúbẹ́nì padà dé ibi kòtò tí ó sì ri pé Jósẹ́fù kò sí níbẹ̀ mọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya pẹ̀lú ìbànújẹ́ Ó padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì wí pé, Ọmọdé-kùnrin náà kò sí níbẹ̀ mọ́! Níbo ni ẹ fẹ́ kí n wọ̀ báyìí Nígbà náà ni wọ́n mú aṣọ Jósẹ́fù, wọ́n pa ewúrẹ́ kan, wọ́n sì tẹ aṣọ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà Wọ́n sì mú aṣọ ọlọ́nà aláràbarà náà pada sí ọ̀dọ̀ baba wọn, wọ́n sì wí pé, A rí èyí he nínú oko, yẹ̀ ẹ́ wò, kí o sì mọ̀ bóyá ti ọmọ rẹ ni Ó sì dá a mọ̀, ó wí pé, Áà! aṣọ ọmọ mi ni, ẹranko búburú ti pa á jẹ, láìṣe àníàní, ó ti fa Jósẹ́fù ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ Nígbà náà ni Jákọ́bù fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì sọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin, lóbìnrin wá láti tù ú nínú, ṣùgbọ́n kò gbà Ó wí pé, Rárá, nínú ọ̀fọ̀ yìí ni èmi yóò lọ sí iṣà òkú lọ́dọ̀ ọmọ mi Baba Jósẹ́fù sì sunkún fún un Ní gbogbo àkókò wọ̀nyí, àwọn ará Mídíánì ta Jósẹ́fù ní Éjíbítì fún Pótífà, ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Fáráò, tí í ṣe olórí ẹ̀sọ́ Júdà àti Támárì Ní àkókò náà, Júdà lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ láti lọ dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin ará Ádúlámù kan tí ń jẹ́ Hírà Júdà sì pàdé ọmọbìnrin Kénánì kan níbẹ ẹni ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Súà Ó sì fi ṣe aya, ó sì bá a lò pọ̀ ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, tí ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Érì Ó sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ónánì Ó sì tún bí ọmọkùnrin mìíràn, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣélà Ní Késíbù ni ó wà nígbà tí ó bí i Júdà sì fẹ́ aya fún Érì, àkọ́bí rẹ̀, orúkọ aya náà ni Támárì Ṣùgbọ́n Érì àkọ́bí Júdà ṣe ènìyàn búburú níwájú Olúwa , Ọlọ́run sì pa á Nígbà náà ni Júdà wí fún Ónánì, Bá aya arákùnrin rẹ lò pọ̀, kí o ṣe ojúṣe rẹ fun un gẹ́gẹ́ bí àbúrò ọkọ, kí ó ba à le bí ọmọ fún un ní orúkọ arákùnrin-ìn rẹ Ṣùgbọ́n Ónání mọ̀ pé àwọn ọmọ náà kì yóò jẹ́ ti òun, nítorí náà ni gbogbo ìgbà tí ó bá wọlé tọ aya arákùnrin rẹ̀ lọ, ilẹ̀ ni ó ń da nǹkan ọkùnrin rẹ̀ sí, kí ó má bá a bímọ fún arákùnrin rẹ̀ Ohun tí ó ń ṣe yìí burú lójú Olúwa , ó sì pa òun náà pẹ̀lú Nígbà náà ni Júdà wí fún Támárì, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, Lọ máa gbé bí opó ní ilé baba rẹ, títí tí Ṣélà yóò fi dàgbà ó lérò pé òun náà lè kú bí àwọn arákùnrin rẹ̀ tó kù Nígbà náà ni Támárì ń lọ gbé ilé baba rẹ̀ Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Júdà, ọmọbìnrin Súà sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Júdà sì pé, ó gòkè lọ sí Tímínà, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hírà ará Ádúlámù tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ Nígbà tí ẹnìkan sọ fún Támárì pé, Baba ọkọ ọ̀ rẹ̀ wà ní ọ̀nà àjò rẹ̀ sí Tímínà láti rẹ́run àgùntàn rẹ̀ Ó bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀ kí wọn má ba à mọ̀ ọ́ Ó sì jókòó sí ẹnu ibodè Énáímù, èyí tí ó wà ní ọ̀nà Tímínà Nítorí ó rí i wí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣélà ti dàgbà, ṣíbẹ̀, a kò fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya Nígbà tí Júdà rí i, ó rò pé aṣẹ́wó ni, nítorí ó ti bo ojú rẹ̀ Láì mọ̀ pé, aya ọmọ òun ní í ṣe, ó yà tọ̀ ọ́, ó wí pé, Kín ni ìwọ yóò fi fún mi kí ìwọ kó lè bá mi lò pọ̀ Ó sì wí pé, Èmi yóò fi ọmọ ewúrẹ́ kan ránṣẹ sí ọ láti inú agbo ẹran Obìnrin náà sì dáhùn pé, Ṣé ìwọ yóò fún mi ní ohun kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí tí ìwọ yóò fi fi ránṣẹ́ Júdà sì bi í pé, Ẹ̀rí wo ni kí n fún ọ Ó sì dáhùn pé, Èdìdì ìdámọ̀ okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ rẹ ti ń bẹ ní ọwọ́ rẹ Ó sì kó wọn fún un, ó sì sùn tì í, obìnrin náà sì lóyún nípaṣẹ̀ rẹ̀ Lẹ́yìn ìgbà tí ó lọ, ó bọ́ ìbòjú ojú rẹ̀, ó sì tún wọ aṣọ opó rẹ̀ padà Nígbà náà ni Júdà fi ọmọ ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí obìnrin náà, kí ó ba à lè rí àwọn nǹkan tí ó fi ṣe ìdúró gbà padà Ṣùgbọ́n wọn kò bá obìnrin náà níbẹ̀ Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àdúgbò náà pé, Níbo ni aṣẹ́wó tí ó wà ní etí ọ̀nà Énáímù wà Wọ́n sì dá a lóhùn pé, Kò sí aṣẹ́wó kankan níbí Ó sì padà lọ sọ́dọ̀ Júdà ó wí fún-un pé, Èmí kò rí i, à ti pé àwọn aládùúgbò ibẹ̀ sọ pé kò sí aṣẹ́wó kankan níbẹ̀ Nígbà náà ni Júdà wí pé, Jẹ́ kí ó máa kó àwọn ohun tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ lọ bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ a ó di ẹlẹ́yà Mo sáà fi ọmọ ewúrẹ́ ránṣẹ́ sí i, ṣùgbọ́n ìwọ kò rí òun Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, wọn sọ fún Júdà pé, Támárì aya ọmọ rẹ̀ ṣe àgbèrè, ó sì ti lóyún Júdà sì wí pé, Ẹ mú un jáde, kí ẹ sì dá iná sun ún Bí wọ́n sì ti ń mú un jáde, ó ránṣẹ́ sí baba ọkọ rẹ̀ pé, Ọkùnrin tí ó ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó fún mi lóyún Wò ó, bóyá o lè mọ ẹni tí ó ni èdìdì ìdámọ̀, okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọ̀nyí Júdà sì dá wọn mọ̀, ó sì wí pé, O ṣe olódodo jù mí lọ, níwọ̀n ìgbà tí n kò fi fún Ṣélà ọmọ mi Kò sì bá a lò pọ̀ mọ́ láti ọjọ́ náà Nígbà tí àsìkò ìbímọ rẹ̀ tó Ìbejì ọkùnrin ni ó bí Bí ó sì ti ń bímọ, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà na ọwọ́ jáde agbẹ̀bí sì so okùn òdòdó mọ́ ọmọ náà ní ọrùn ọwọ́ Ó sì wí pé, Èyí ni o kọ́kọ́ jáde Ṣùgbọ́n nìgbá tí ó fa ọwọ́ rẹ̀ padà, èkejì rẹ̀ jáde Támárì sì wí pé, Níbo ni ìwọ ti wá Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Pérésì Nígbà náà ni èkejì tí a ti so okùn olódòdó mọ́ lọ́rùn ọwọ́ jáde, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ni Ṣérà Jósẹ́fù àti Aya Pọ́tífà Nígbà tí wọ́n mú Jósẹ́fù dé Éjíbítì, Pótífà, ará Éjíbítì tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Fáráò Òun ni olórí àwọn ọmọ ogun Fáráò Ó ra Jósẹ́fù lọ́wọ́ àwọn ará Íṣímáẹ́lì tí wọ́n mú-un lọ ṣíbẹ̀ Olúwa sì wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì bùkún-un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Éjíbítì Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé Jósẹ́fù sì rí ojúrere Pọ́tífà, ó sì di asojú rẹ̀, Pọ́tífà fi Jósẹ́fù ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní Láti ìgbà tí ó ti fi Jósẹ́fù jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun-ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún-un nítorí Jósẹ́fù Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Pọ́tífà ní, nílé àti lóko Ó sì fi Jósẹ́fù ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Jósẹ́fù ṣe àkóṣo ilé e rẹ̀ Josẹ́fù sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀, lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Jósẹ́fù, ó sì wí fún un pé, Wá bá mi lò pọ̀! Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́ Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀ Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Jósẹ́fù, Jósẹ́fù kọ̀ láti bá a lò pọ̀ Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà Ní ọjọ́ kan, Jósẹ́fù lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí Ó sì di aṣọ Jósẹ́fù mú, ó sì wí pé, Wá bá mi lò pọ̀! Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde, ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Ébérù kan wọlé tọ̀ wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lò pọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sokè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé Ó rò fún un pé, Ẹrú ará a Ébérù tí o rà wálé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lò pọ̀ Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé Nígbà tí Pọ́tífà gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi Ó sì ju Jósẹ́fù sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí Ṣùgbọ́n, nígbà tí Jóṣẹ́fù wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì sàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Jọ́ṣẹfù ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń se níbẹ̀ Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Jósẹ́fù, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ lé Káínì àti Ábélì Ádámù sì bá aya rẹ̀ Éfà lò pọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Káínì Ó wí pé, Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa ni mo bí ọmọkùnrin Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Ábélì Ábélì jẹ́ darandaran, Káínì sì jẹ́ àgbẹ̀ Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Káínì mú ọrẹ wá fún Olúwa nínú èṣo ilẹ̀ rẹ̀ Ṣùgbọ́n Ábélì mú ẹran tí ó sanra wá fún Olúwa nínú àkọ́bí ẹran-ọ̀sìn rẹ̀ Olúwa sì fi ojú rere wo Ábélì àti ọrẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò fi ojú rere wo Káínì àti ẹbọ rẹ̀ Nítorí náà inú bí Káínì gidigidi, ojú rẹ̀ sì fàro Nígbà náà ni Olúwa bi Káínì pé, Èéṣe tí ìwọ ń bínú Èéṣe tí ojú rẹ sì fàro Bí ìwọ ba ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀ Káínì wí fún Ábélì arákùnrin rẹ̀ pé, Jẹ́ kí a lọ sí oko Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko Káínì da ojú ìjà kọ Ábélì arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á Nígbà náà ni Olúwa béèrè lọ́wọ́ Káínì pé, Níbo ni Ábélì arákùnrin rẹ wà Ó sì dáhùn pé, Èmi kò mọ ibi tí ó wà, èmí ha ń ṣe olùṣọ́ arákùnrin mi bí Olúwa wí pé, Kín ni ohun tí ìwọ ṣe yìí Gbọ́! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti ilẹ̀ wá Láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ ti wà lábẹ́ ègún, a sì ti lé ọ lórí ilẹ̀ tí ó ya ẹnu gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ lọ́wọ́ rẹ Bí ìwọ bá ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀, ilẹ̀ kì yóò so èṣo rẹ̀ fún ọ mọ́ Ìwọ yóò sì jẹ́ ìsáǹsá àti alárìnkiri ni orí ilẹ̀ ayé Káínì wí fún Olúwa pé, Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ Lónìí, ìwọ lé mi kúrò lórí ilẹ̀, mó sì di ẹni tí ó fara pamọ́ kúrò ní ojú rẹ, èmi yóò sì di ìsáǹsá àti alárìnkiri ní ayé, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi, yóò sì pa mí Ṣùgbọ́n, Olúwa wí fún pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ẹnikẹ́ni bá pa Káínì, èmi yóò gbẹ̀san ní ara onítọ̀hún ní ìgbà méje Nígbà náà ni Ọlọ́run fi àmì sí ara Káínì, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí má ba pa á Káínì sì kúrò níwájú Ọlọ́run, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nódì ní ìhà ìlà oòrùn Édẹ́nì Káínì sì bá aya rẹ̀ lò pọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Énókù Káínì sì tẹ ìlú kan dó, ó sì fi orúkọ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Énókù sọ ìlú náà Énókù sì bí Írádì, Írádì sì ni baba Méhújáélì, Méhújáélì sì bí Métúsáélì, Métúsáélì sì ni baba Lámékì Lámékì sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkíní ni Ádà, àti orúkọ èkejì ni Ṣílà Ádà sì bí Jábálì òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran-ọ̀sìn Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Júbálì, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè Ṣílà náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Káínì, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin Arábìnrin Tubali-Káínì ni Náámà Lámékì wí fún àwọn aya rẹ̀, Ádà àti Ṣílà, ẹ tẹ́tí sí mi ẹ̀yin aya Lámékì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára Bí a ó bá gbẹ̀san Káínì ní ìgbà méje, ǹjẹ́ kí a gba ti Lámékì nígbà àádọ́rin-lé-méje Ádámù sì tún bá aya rẹ̀ lò pọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣẹ́tì, tí ó túmọ̀ sí pé, Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Ábélì tí Káínì pa Ṣẹ́tì náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Énọ́sì Láti àkókò náà lọ ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe orúkọ Olúwa Agbọ́tí àti Alásè Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, ni agbọ́tí ọba àti alásè rẹ̀ ṣẹ ọba Éjíbítì, olúwa wọn Fáráò sì bínú sí méjì nínú àwọn ìjòyè rẹ̀, olórí agbọ́tí àti olórí alásè, Ó sì fi wọ́n sí ìhámọ́ ní ilé olórí ẹ̀sọ́, ní inú ẹ̀wọ̀n ibi tí Jósẹ́fù pẹ̀lú wà Olórí ẹ̀sọ́ sì yan Jósẹ́fù láti máa ṣe ìránṣẹ́ wọn Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wà ní ìhámọ́ fún ìgbà díẹ̀ Ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin méjèèjì náà-olórí agbọ́tí àti olórí alásè lá àlá, ní òru kan náà, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀ Nígbà tí Jósẹ́fù dé ọ̀dọ̀ wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó ṣe àkíyèsí pé, inú wọn kò dùn Ó sì bi àwọn ìjòyè Fáráò tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn Wọ́n wí pé, Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀ Jósẹ́fù sì wí fún wọn pé, Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtúmọ̀ Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Jósẹ́fù, wí pé, Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan níwájú mi, Mo sì rí ẹ̀ka mẹ́ta lórí àjàrà náà, ó yọ ẹ̀ka tuntun, ó sì tanná, láìpẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní èso tí ó ti pọ́n Ife Fáráò sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èṣo àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Fáráò, mo sì gbé ife náà fún Fáráò Jósẹ́fù wí fún-un pé, Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta Láàrin ọjọ́ mẹ́ta Fáráò yóò mú ọ jáde nínú ẹ̀wọ̀n padà sí ipò rẹ, ìwọ yóò sì tún máa gbọ́tí fún-un, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ àtẹ̀yìnwá Ṣùgbọ́n nígbà tí ohun gbogbo bá dára fún ọ, rántí mi kí o sì fi àánú hàn sí mi Dárúkọ mi fún Fáráò, kí o sì mú mi jáde kúrò ní ìhín Nítorí á jí mi gbé tà kúrò ní ilẹ̀ àwọn Ébérù ni, àti pé níhìnín èmi kò ṣe ohunkóhun tí ó fi yẹ kí èmi wà ní ìhámọ́ bí mo ti wà yìí Nígbà tí olórí alásè rí i wí pé ìtúmọ̀ tí Jósẹ́fù fún àlá náà dára, ó wí fún Jósẹ́fù pé, Èmi pẹ̀lú lá àlá Mo ru agbọ̀n oúnjẹ mẹ́ta lórí, Nínú agbọ̀n tí ó wà lókè, onírúurú oúnjẹ ló wà níbẹ̀ fún Fáráò, ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ sì ń ṣà wọ́n jẹ láti inú apẹ̀rẹ̀ náà tí ó wà lórí mi Jósẹ́fù dáhùn, Èyí ni ìtúmọ̀ àlá rẹ Agbọ̀n mẹ́ta náà túmọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta Láàrin ọjọ́ mẹ́ta, Fáráò yóò tú ọ sílẹ̀, yóò sì bẹ́ orí rẹ, yóò sì gbé ara rẹ kọ́ sí orí igi Àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ara rẹ Ọjọ́ kẹ́ta sì jẹ́ ọjọ́ ìbí Fáráò, ó sì ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀ Ó sì mú olórí agbọ́tí àti olórí aláṣè jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n Ó dá olórí agbọ́tí padà sí ipò tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ó ba à le máa ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bí i ti àtẹ̀yìnwa, Ṣùgbọ́n, ó so olórí alásè kọ́ sórí igi, gẹ́gẹ́ bí Jósẹ́fù ti sọ fún wọn nínú ìtúmọ̀ rẹ̀ sí àlá wọn Ṣùgbọ́n, olórí agbọ́tí kò rántí Jósẹ́fù mọ́, kò tilẹ̀ ronú nípa rẹ̀ Àwọn àlá Fáráò Nígbà tí odindi ọdún méjì sì ti kọjá, Fáráò lá àlá ó rí ara rẹ̀ tó dúró ní etí odò Náílì Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Náílì, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà Àwọn màlúù tí ó rù, tí kò sì lẹ́wà sì gbé àwọn tí ó lẹ́wà tí ó sanra jẹ Nígbà náà ni Fáráò jí Ó sì tún padà sùn, ó sì lá àlá mìíràn ó rí siírì ọkà méje tí ó kún, ó yó'mọ, ó sì dára, ó sì jáde lára igi ọkà kan ṣoṣo Lẹ́yìn wọn ni síírí ọkà méje mìíràn yọ, wọn kò yó'mọ, afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù Àwọn sìírì ọkà méje tí kò yó'mọ wọ̀nyí sì gbé àwọn tí ó yó'mọ mì Nígbà náà ni Fáráò jí lójú oorun, ó sì rí i pé àlá ni Ní òwúrọ̀, ọkàn rẹ̀ dàrú, nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn onídán àti ọ̀mọ̀ran ilẹ̀ Éjíbítì Fáráò rọ́ àlá rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n kò rí ọ̀kan nínú wọn tí ó le sọ ìtúmọ̀ àlá náà fún un Nígbà náà ni olórí agbọ́tí wí fún Fáráò pé, Lónìí ni mo rántí àìṣedéédé mi Nígbà kan tí Fáráò bínú sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì fi èmi àti olórí alásè sínú ẹ̀wọn ní ilé olórí ẹ̀sọ́ Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lá àlá, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀ Ọmọkùnrin ará Hébérù kan tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ olórí ẹ̀sọ́ wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa A ṣọ́ àwọn àlá wa fún un, ó sì túmọ̀ wọn fún wa, ó sọ ìtúmọ̀ àlá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un Bí ó sì ti túmọ̀ àlá wọ̀nyí náà ni ohun gbogbo rí A dá mi padà sí ipò mi, a sì ṣo ọkùnrin keji kọ́ sórí òpó Nítorí náà Fáráò ránṣẹ́ pe Jósẹ́fù, wọn sì mu un wá kíákíá láti inú ìhámọ́ Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, s tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá ṣíwájú Fáráò Fáráò wí fún Jósẹ́fù, Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀ Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀ Jóṣẹ́fù dáhùn pé, kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fún Fáráò ní ìtúmọ̀ àlá náà Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jóṣẹ́fu pé, Ní inú àlá mi, mo dúró ni etí bèbè odò Náílì, sì kíyèsí i, màlúù méje tí ó sanra tí o sì lẹ́wà jáde wá, wọ́n sì ń jẹ koríko ní tòsí ibẹ̀ Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógo, wọn kò sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí n kò tíì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Éjíbítì Àwọn màlúù tí ó rù tí kò sì lẹ́wà sì jẹ àwọn màlúù tí ó sanra tí ó kọ́ jáde nínú odò Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ́ wọ́n tan, kò sì ẹni tí ó le mọ̀ pé wọ́n jẹ ohunkóhun, nítorí wọn kò sanra sí i, wọn sì búrẹ́wà ṣíbẹ̀ Nígbà náà ni mo jí lójú oorun mi Ní ojú àlá mi, mo tún rí ṣiiri ọkà méje tí ó yó ọmọ tí ó sì dára, wọ́n jáde láti ara igi ọkà kan Lẹ́yìn wọn, àwọn méje mìíràn yọ jáde, tí kò yó ọmọ bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù tán Àwọn siiri ọkà méje tí kò yó mọ sì gbé àwọn méje tí ó dára wọ̀nyí mì Mo ṣọ àlá yìí fún àwọn onídán àn mi, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó le è túmọ̀ rẹ̀ fún mi Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún Fáráò, Ìtúmọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Fáráò Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, ṣiiri ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni siiri ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrun ti rẹ̀ dànù tan Wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú Bí mo ti wí fún Fáráò ní ìṣáájú náà ni Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Fáráò Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ yanturu ń bọ̀ wà ní Éjíbítì Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú yóò tẹ̀lé e, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé pé ọdún méje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà yanturu tilẹ̀ ti wà rí, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà, A kò ní rántí àsìkò ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu náà mọ́ nítorí pé ìyàn tí yóò tẹ̀lé e yóò pọ̀ púpọ̀ Ìdí tí Ọlọ́run fi fi àlá náà han fún Fáráò ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pé, Ọlọ́run ti pinnu pé yóò sẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ dandan, àti pé kò ni pẹ́ tí Ọlọ́run yóò fi ṣe é Ìmọ̀ràn mi ni wí pé, jẹ́ kí Fáráò wá ọlọgbọ́n ènìyàn kan ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí ó sì fi ṣe alákòóṣo iṣẹ́ àgbẹ̀ ilẹ̀ Éjíbítì Kí Fáráò sì yan àwọn alábojútó láti máa gba idá márùn-ún ìkórè oko ilẹ̀ Éjíbítì ní àsìkò ọdún méje ọ̀pọ̀ Kí wọn kó gbogbo oúnjẹ ilẹ̀ náà ni àwọn ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, kí wọn sì kó àwọn ọkà tí wọn jẹ sẹ́kù pamọ́ lábẹ́ aṣẹ Fáráò Kí a kó wọn pamọ́ ni àwọn ìlú fún jíjẹ Kí wọn kó oúnjẹ náà pamọ́ fún orílẹ̀ èdè yìí, kí a baà le lò ó ni ọdún méje tí ìyàn yóò fi jà ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí ìyàn náà má ba à pa orílẹ̀ èdè yìí run Èrò náà sì dára lójú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ Fáráò sì bi wọ́n pé, Ǹjẹ́ a le rí ẹnikẹ́ni bi ọkùnrin yìí, nínú ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jósẹ́fù, Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti fi gbogbo èyí hàn ọ, kò sí ẹni náà tí ó gbọ́n tí ó sì mọ̀ràn bí i tìrẹ ní ilẹ̀ Éjíbítì yìí, ìwọ yóò ṣe àkóso ààfin mi gbogbo àwọn ènìyàn gbọdọ̀ tẹríba fún àṣẹ ẹ̀ rẹ Ìtẹ́ mi nìkan ni èmi yóò fi jù ọ́ lọ Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé, Mo fi ọ́ ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì Fáráò sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Jósẹ́fù ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn Ó sì mú un kí ó gun kẹ̀kẹ́ ẹsin bí igbàkejì ara rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń pariwo níwájú rẹ̀ pé, Ẹ yàgò lọ́nà Báyìí ni ó sì fi ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jóṣẹ́fù pé, Èmi ni Fáráò Ṣùgbọ́n láì sí àṣẹ rẹ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun ní ilẹ̀ Éjíbítì Fáráò sì sọ Jósẹ́fù ní orúkọ yìí Ṣefunati-Páníà èyí tí ó túmọ̀ sí, , Ó sì fun un ní Áṣénátì ọmọ Pótífẹ́rà, alábojútó òrìṣà Ónì, gẹ́gẹ́ bí aya Jósẹ́fù sì rin gbogbo ilẹ̀ náà já Ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni Jósẹ́fù nígbà tí ó wọ iṣẹ́ Fáráò ọba Éjíbítì Jósẹ́fù sì jáde kúrò níwájú Fáráò, ó sì ṣe ìbẹ̀wò káàkiri gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì Ní ọdún méje ọ̀pọ̀, ilẹ̀ náà ṣo èso lọ́pọ̀lọpọ̀ Jóṣẹ́fù kó gbogbo oúnjẹ tí a pèṣè ni ilẹ̀ Éjíbítì ní ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, ó sì pa wọ́n mọ́ sí àwọn ìlú Ní ìlú kọ̀ọ̀kan ni ó kó gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbìn ní àyíká ìlú wọn sí Jósẹ́fù pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà mọ́ bí i yanrìn òkun ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò ṣe àkọsílẹ̀ mọ́ nítorí, ó tayọ kíkà Kí ó tó di pé ọdún ìyàn dé, Áṣénátì ọmọ Pótífẹ́rà alábojútó Ónì bí ọmọkùnrin méjì fún Jósẹ́fù Jósẹ́fù sọ orúkọ àkọ́bí rẹ̀ ni Mánásè, ó sì wí pé, Nítorí tí Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìdààmú mi àti gbogbo ilé baba mi Ó sì sọ orúkọ èkejì ní Éfúráímù, ó sì wí pé, Nítorí pé Ọlọ́run fún mi ní ọmọ ní ilẹ̀ ìpọ́njú mi Ọdún méje ọ̀pọ̀ oúnjẹ sì wá sí òpin ní ilẹ̀ Éjíbítì, Ọdún méje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀, bí Jósẹ́fù ti wí gan-an Ìyàn sì mú ní gbogbo ilẹ̀ tó kù, ṣùgbọ́n oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì Nígbà tí àwọn ará Éjíbítì bẹ̀rẹ̀ sí ní rí ipá ìyàn náà, wọ́n kígbe sí Fáráò Nígbà náà ni Fáráò wí fún wọn pé, Ẹ lọ bá Jóṣẹ́fù, ẹ ṣe ohun tí ó bá wí fún un yín Nígbà tí ìyàn sì ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà, Jósẹ́fù sí inú àká, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ìyàn náà mú gan-an ní gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè sì ń wá láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Jósẹ́fù, nítorí ìyàn náà pọ̀ gidigidi káàkiri gbogbo ayé Àwọn Arákùnrin Jósẹ́fù Lọ Sí Éjíbítì Nígbà tí Jákọ́bù mọ̀ pé ọkà wà ní Éjíbítì, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán Mo tí gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Éjíbítì Ẹ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibẹ̀ kí ẹ sì rà wá fún wa, kí a má ba à kú Nigbà náà ni mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin Jósẹ́fù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì láti ra ọkà Ṣùgbọ́n Jákọ́bù kò rán Bẹ́ńjámínì àbúrò Jósẹ́fù lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bàá kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ síi Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lára àwọn tó lọ Éjíbítì lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kénánì pẹ̀lú Nisinsin yìí, Jósẹ́fù ni alábojútó fún gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, òun sì ni ó ń bojú tó ọkà títà fún gbogbo ènìyàn ìlú náà Nítorí náà nígbà tí àwọn arákùnrin Jóṣẹ́fù dé, wọ́n tẹríba, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Jósẹ́fù Gbàrà tí Jósẹ́fù ti rí àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó ti dá wọn mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe bí i wí pé kò mọ̀ wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ líle sí wọn Ó béèrè pé, Níbo ni ẹ ti wá Wọ́n sì dáhùn pé, Láti ilẹ̀ Kénánì ni a ti wá ra oúnjẹ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Jósẹ́fù mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, ṣíbẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kò mọ̀ ọ́n Nígbà náà ni ó rántí àlá rẹ̀ tí ó lá sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, Ayọ́lẹ̀wò ni yín, ẹ wá láti wo àsírí ilẹ̀ wa ni Wọ́n dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́ olúwa wa, àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá láti ra oúnjẹ ni, Ọmọ baba ni wá, olóòótọ́ ènìyàn sì ni wá pẹ̀lú, àwa kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò Ó wí fún wọn pé, Rárá! Ẹ wá láti wo àsírí ilẹ̀ wa ni Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kénánì Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú Jósẹ́fù wí fún wọn pé, Bí mo ti wí fún un yín náà ni Ayọ́lẹ̀wò ni yín! Èyí sì ni a ó fi dán-an yín wò, èmi búra pé, níwọ̀n ìgbà tí Fáráò bá wà láàyè, ẹ kì yóò kùró níbí, àyàfi bí arákùnrin yín kan tókù bá wá síbí Ẹ rán ọ̀kan nínú yín lọ láti mú arákùnrin yín wá, àwa yóò fi ẹ̀yin tókù pamọ́ sínú àtìmọ́lé, kí àwa ba à lè mọ bóyá òtítọ́ ni ẹ̀yin ń wí Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé irọ́ ni ẹ̀yin ń pa, ní òtítọ́ bí Fáráò ti ń bẹ láàyè ayọ́lẹ̀wò ni yín! Ó sì fi gbogbo wọn sínú àtìmọ́lé fún ọjọ́ mẹ́ta Ní ọjọ́ kẹ́ta, Jósẹ́fù wí fún wọn pé, Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe kí ẹ̀yin ba à le yè nítorí mo bẹ̀rù Ọlọ́run Tí ó bá jẹ́ pé olótìítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ jẹ́ kí ọkan nínú yín dúró ni àtìmọ́lé ní ìhín, nígbà tí àwọn yókù u yín yóò gbé ọkà lọ fún àwọn ará ilé e yín tí ebi ń pa Ṣùgbọ́n ẹ gbọdọ̀ mú arákùnrin tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn yín wá, kí n ba à le mọ òtítọ́ ohun ti ẹ ń wí, kí ẹ má baà kú Wọn sì gbà láti ṣe èyí Wọ́n ń sọ ọ́ láàrin ara wọn wí pé, Dájúdájú a ń jìyà nítorí ohun tí a ṣe sí Jósẹ́fù A rí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbẹ́bẹ̀, nítorí náà ni ìdààmú yìí fi dé bá wa Rúbẹ́nì fèsì pé, Ǹjẹ́ ń ò wí fún yín pé kí ẹ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ọmọdé-kùnrin náà Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́! Nisinsin yìí a ń béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ wa Wọn kò sì mọ̀ pé, Jósẹ́fù ń gbọ́ wọn ní àgbọ́yé nítorí ògbufọ̀ ni ó ń lò tẹ́lẹ̀ Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ Ó mú Símónì kúrò láàrin wọn, ó sì dè é ní ojú wọn Jósẹ́fù pàṣẹ pé kí wọn bu ọkà kún inú àpò wọn, kí wọn sì mú owó ẹnìkọ̀ọ̀kan padá sínú àpò rẹ̀, kí wọn sì fún wọn ní ohun tí wọn yóò lò nírín-àjò wọn padá sílé Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe èyí fún wọn, Wọn gbé ẹrù wọn lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọn sì padà lọ sí ilé Níbi tí wọ́n ti dúró láti sùn lóru ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú wọn tú àpò rẹ̀ láti mú oúnjẹ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì rí owó rẹ̀ ní ẹnu àpò rẹ̀ Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Jákọ́bù baba wọn, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí ó sẹlẹ̀ fún-un wí pé, Ọkùnrin náà tí í ṣe alábojútó ilẹ̀ náà, sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó sì fi ẹ̀sùn kàn wá pé a wá yọ́ ilẹ̀ náà wò ni Ṣùgbọ́n, a wí fun-un pé, Rárá o, olóòtọ́ ènìyàn ni wá, a kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò Arákùnrin méjìlá ni wá, ọmọ bàbá kan náà, ọ̀kan ti kú, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wà lọ́dọ̀ baba wa ni ilẹ̀ Kénánì Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó jẹ́ alábojútó ilẹ̀ náà wí fún wa pé, Báyìí ni n ó ṣe mọ̀ bóyá olóòótọ́ ènìyàn ni yín Ẹ fi ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ níbí, pẹ̀lú mi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ fún àwọn ará ilé yín tí ebi ń pa kú lọ, lọ́wọ́ ìyàn Ṣùgbọ́n ẹ mú arákùnrin yín tí ó kéré jù lọ wá fún mi kí n le mọ̀ pé dájúdájú ẹ kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò bí kò ṣe ènìyàn tòótọ́ Nígbà náà ni n ó mú arákùnrin yín pada fún un yín, lẹ́yìn náà ẹ le máa wá ṣe òwò bí ó ti wù yín ní ilẹ̀ yìí   Bí wọ́n sì ti ń tú àpò ẹrù wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan bá owó tí ó san fún ọjà náà lẹ́nu àpò rẹ̀! Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi, àwọn àti baba wọn Jákọ́bù bàbá wọn wí fún wọn pé, Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi N kò rí Jósẹ́fù mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n ò kò sì rí Símónì náà mọ Ẹ sì tún fẹ́ mú Bẹ́ńjámínì lọ! Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí Nígbà náà ni Rúbẹ́nì wí fún bàbá rẹ̀ pé, Pa àwọn ọmọ mi méjèèjì bí n kò bá mú Bẹ́ńjámínì padà wá fún ọ, èmi ni kí o fà á lé lọ́wọ́, n ó sì mu-un padà wá Ṣùgbọ́n Jákọ́bù wí pé, Ọmọ mi kì yóò bá a yín lọ, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nikan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ Bí ohunkóhun bá sẹlẹ̀ sí i, ìbànújẹ́ ni yóò sì pa mi kú ni ọjọ́ ogbó mi yìí Ìrìnàjò ẹ̀ẹ̀kejì lọ sí Éjíbítì Báyìí, ìyàn náà sì mú gidigidi ní ilẹ̀ náà Nígbà tí wọ́n sì ti jẹ gbogbo ọkà tí wọ́n rà ní Éjíbítì tan, baba wọn wí fún wọn pé, Ẹ padà lọ ra oúnjẹ́ díẹ̀ si wá fún wa Ṣùgbọ́n Júdà wí fún un pé, Ọkùnrin náà tẹnumọ́ ọn nínú ìkìlọ̀ rẹ̀ fún wa pé, Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́, àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá Tí ìwọ yóò bá rán Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa lọ pẹ̀lú wa, a ó lọ ra oúnjẹ wá fún ọ Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ni jẹ́ kí ó bá wa lọ, àwa kì yóò lọ, nítorí ọkùnrin náà sọ fún wa pé, Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́ àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá   Ísírẹ́lì béèrè pé, Èéṣe tí ẹ fi kó ìdààmú yìí bá mi nípa sísọ fún ọkùnrin náà wí pé ẹ ní arákùnrin mìíràn Wọ́n dáhùn pé, Ọkùnrin náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí lọ́wọ́ wa nípa ìdílé wa àti àwa fúnra wa Ó béèrè pé, Ṣe bàbá yín sì wà láàyè Ǹjẹ́ ẹ tún ní arákùnrin mìíràn A kàn dáhùn ìbéèrè rẹ̀ ni Báwo ni a ṣe le mọ̀ pé yóò wí pé, Ẹ mú arákùnrin yín wá Júdà sì wí fún Ísírẹ́lì bàbá rẹ̀, Jẹ́ kí ọmọkùnrin náà lọ pẹ̀lú mi, a ó sì lọ ní kíákíá, kí àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ wa le yè, kí a má sì kú Èmi fúnra mi yóò ṣe onídùúró fún un, èmi ni kí o gbà pé o fi lé lọ́wọ́ Bí n kò bá sì mu un padà tọ̀ ọ́ wá, jẹ́ kí ẹ̀bi rẹ̀ kí ó jẹ́ tèmi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi níwájú rẹ Bí ó bá ṣe pé a kò fi falẹ̀ ni, àwa ì bá ti lọ, à bá sì ti padà ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Nígbà náà ni Ísírẹ́lì baba wọn wí fún wọn, Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe Ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà-ìpara díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjíá, èso Písítakíò àti eso álímíndì ìlọ́po owó méjì ni kí ẹ mú lọ́wọ́, nítorí ẹ gbọdọ̀ dá owó tí ẹ bá lẹ́nu àpò yín padà Bóyá ẹnìkan ló sèèsì fi ṣíbẹ̀ Ẹ mú arákùnrin yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ki ẹ sì tọ arákùnrin náà lọ Kí Ọlọ́run alágbára jẹ́ kí ẹ rí àánú gbà lọ́dọ̀ ọkùnrin náà kí ó ba à le jẹ́ kí arákùnrin yín tí ó wà lọhun-un àti Bẹ́ńjámínì padà wá pẹ̀lú yín Ní tèmi, bí mo bá pàdánù àwọn ọmọ mi, n ó sọ̀fọ̀ wọn náà ni Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹ̀bùn náà àti owó ìlọ́po méjì àti Bẹ́ńjámínì, wọ́n sì yára lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Jóṣẹ́fù Nígbà tí Jóṣẹ́fù rí Bẹ́ńjámínì pẹ̀lú wọn, ó sọ fún ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, Mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ sí ilé mi, pa ẹran kí o sì se àsè wọn ó jẹun ọ̀sán pẹ̀lú mi Ọkùnrin náà sì ṣe bí Jósẹ́fù ti wí fún un, ó sì mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Jósẹ́fù Ẹ̀rù sì ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Jósẹ́fù Wọ́n rò ó pé, A mú wa wá sí ìhín nítorí owó tí a fi sí inú àpò wa ní ìgbà àkọ́kọ́ Ó fẹ́ bá wa jà, kí ó mú wa lẹ́rú kí ó sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa Nítorí náà wọ́n lọ bá ìránṣẹ́ Jósẹ́fù, wọ́n sì ba sọ̀rọ̀ ní ẹnu ọ̀nà à bá wọlé ilé náà Wọ́n wí pé, Jọ̀wọ́ ọ̀gá Ní ìgbà àkọ́kọ́ tí a wá ra oúnjẹ Ṣùgbọ́n níbi tí a ti dúró ní ọ̀nà láti sùn ní alẹ́, nígbà tí a tú àpò oúnjẹ wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá owó oúnjẹ tirẹ̀ tí ó rà lẹ́nu àpò láì lé, láì dín Nítorí náà òun nìyí, a ti mu-un padà wá pẹ̀lú wa A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ láti fi ra oúnjẹ A ò mọ ẹni tí ó fi owó wa sí ẹnu àpò Ó dáhùn pé, Ó dára, ẹ má bẹ̀rù, Ọlọ́run yín, àní Ọlọ́run baba yín ni ó fi ìsúra sí inú àpò yín mo rí owó tí ẹ san gbà Nígbà náà ni ó mú Símónì jáde tọ̀ wọ́n wá Ìránṣẹ́ náà mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Jósẹ́fù, ó fún wọn ní omi láti fi wẹ ẹsẹ̀ wọn nu, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn lóúnjẹ pẹ̀lú Wọ́n pèṣè ẹ̀bùn wọn sílẹ̀ fún Jósẹ́fù di ọ̀sán nígbà tí yóò dé, nítorí wọ́n ti gbọ́ pé ibẹ̀ ni àwọn yóò ti jẹun ọ̀sán Nígbà tí Jósẹ́fù dé sí ilé, wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ti mú wá fún-un, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ Ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì wí pé, Ṣé àlàáfíà ni baba yín wà, baba arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣé ó sì wà láàyè Wọ́n dáhùn pé, Ìránṣẹ́ rẹ, baba wa sì wà láàyè, àlàáfíà sì ni ó wà pẹ̀lú Wọn sì tẹríba láti bọ̀wọ̀ fún un Bí ó ti wo yíká tí ó sì rí Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀, tí í ṣe ọmọ ìyá rẹ̀ gan-an Ó béèrè lọ̀wọ̀ wọn pé, Ṣe àbúrò yín tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn tí ẹ sọ fún mi nípa rẹ̀ nìyìí Ó sì tún wí pe, Kí Ọlọ́run kí ó sàánú fún ọ, ọmọ mi Ọkàn rẹ̀ sì fà sí i gidigidi nígbà tí ó rí arákùnrin rẹ̀, nítorí náà Jósẹ́fù yára jáde láti wá ibi tí ó ti le sunkún Ó lọ sí iyàrá rẹ̀, ó sì sunkún níbẹ̀ Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti bọ́jú tan, ó jáde wá, ó ṣe ọkàn ọkùnrin, ó sì wí fún wọn pé, kí wọ́n gbé oúnjẹ wá kí wọ́n le è jẹun Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ fun-un lọ́tọ̀, àti fún àwọn ará Éjíbítì tí ó wá ba jẹun náà lọ́tọ̀, nítorí ará Éjíbítì kò le bá ará Ébérù jẹun nítorí ìríra pátapáta ló jẹ́ fún àwọn Éjíbítì A mú àwọn ọkùnrin náà jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bí wọ́n ṣe dàgbà sí, láti orí ẹ̀gbọ́n pátapáta dé orí èyí tí ó kéré pátapáta, wọ́n sì ń wo ara wọn tìyanu tìyanu A sì bu oúnjẹ fún wọn láti orí tábìlì Jósẹ́fù Oúnjẹ Bẹ́ńjámínì sì tó ìlọ́po márùn-ùn ti àwọn tókù Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu lọ́dọ̀ rẹ̀ láì sí ìdíwọ́ Kọ́ọ̀bù Idẹ Nínú Àpò Nígbà náà ni Jósẹ́fù pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Di oúnjẹ kún inú àpò àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n èyí tí wọ́n le rù, kí o sì mú owó olúkúlukù àwọn ọkùnrin náà padà sí ẹnu àpò rẹ̀ Nígbà náà ni kí o mú kọ́ọ̀bù idẹ mi sí ẹnu àpò èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn nínú wọn pẹ̀lú owó tí ó fi ra ọkà, ó sì ṣe bí Jósẹ́fù ti sọ Bí ilẹ̀ ti ń mọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn padà lọ pẹ̀lù kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn Wọn kò tí ì rìn jìnnà sí ìlú náà tí Jósẹ́fù fi wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Lépa àwọn ọkùnrin náà, nígbà tí o bá sì bá wọn, kí o wí pé, Èéṣe ti ẹ fi búburú san rere Èyí ha kọ́ ni kọ́ọ̀bù tí olúwa mi ń lò fún ohun mímu tí ó sì tún ń fi í ṣe àyẹ̀wò Ohun tí ẹ ṣe yìí burú púpọ̀   Nígbà tí ó sì bá wọn, o sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn Ṣùgbọ́n wọ́n dá a lóhùn pé, Kín ló dé tí olúwa mi sọ irú nǹkan wọ̀nyí Ká má rí i! Àwọn ìránṣẹ́ rẹ kò le ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! A tilẹ̀ mú owó tí a rí lẹ́nu àpò wa padà tọ̀ ọ́ wá láti ilẹ̀ Kénánì Nítorí náà èéṣe tí àwa yóò fi jí wúrà tàbí idẹ ní ilé olúwa à rẹ Bí a bá rí i lọ́wọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kíkú ni yóò kú, àwọn tí ó kù yóò sì di ẹrú fún olúwa à rẹ Ó wí pé, Ó dára, kí ó rí bí ẹ ti ṣe sọ Ẹnikẹ́ni tí mo bá rí i lọ́wọ́ rẹ̀ yóò di ẹrú mi Ẹ̀yin tí ó kù yóò sì wà láì lẹ́bi Olúkúlùkù wọn yára sọ àpò rẹ̀ kalẹ̀, wọ́n sì tú u Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní í wá a, bẹ̀rẹ̀ láti orí ẹ̀gbọ́n títí lọ sórí àbúrò pátapáta Ó sì rí kọ́ọ́bù náà nínú àpò ti Bẹ́ńjámínì Nígbà tí wọ́n rí èyí, wọ́n fa aṣọ wọn ya , wọn tún ẹrù wọn dì sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì padà sí inú ìlú Jósẹ́fù sì wà nínú ilé nígbà tí Júdà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wọlé wá Gbogbo wọn sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ Jósẹ́fù wí fún wọn pé, Èwo ni èyí tí ẹ ṣe yìí Ṣe ẹ kò mọ pé, ènìyàn bí èmi le è rí ìdí nǹkan nípa ṣiṣe àyẹ̀wò Júdà dáhùn pé, Kín ni à bá sọ fún olúwa mi Báwo ni a ṣe lè wẹ ara wa mọ́ Ọlọ́run ti tú àsírí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, a ti di ẹrú olúwa à mi báyìí-àwa fúnra wa àti ẹni náà tí a rí kọ́ọ̀bù lọ́wọ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù dáhùn pé, Ká má rí i pé mo ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! Ẹni tí a bá kọ́ọ̀bù mi lọ́wọ́ rẹ̀ nìkan ni yóò di ẹrú mi, ẹ̀yin tí ó kù, ẹ máa lọ sọ́dọ̀ baba yín ní àlàáfíà Nígbà náà ni Júdà sún mọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, Jọ̀wọ́ olúwa mi, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó sọ ọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi, má ṣe bínú sí ìránṣẹ́ rẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ pẹ̀lú láṣẹ bí i ti Fáráò Olúwa mi béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Ǹjẹ́ ó ní baba tàbí arákùnrin A sì dáhùn pé, A ni baba tí ó ti darúgbó, ọmọkùnrin kan sì wà pẹ̀lú tí a bí fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn an rẹ̀ Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ mu-un tọ̀ mí wá kí n le fojú ara mi rí i A sì sọ fún olúwa à mi pé, Ọmọkùnrin náà kò le è fi baba rẹ̀ sílẹ̀, bí ó bá dán-an wò baba rẹ̀ yóò kú Ṣùgbọ́n ìwọ wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ má ṣe padà tọ̀ mí wá àyàfi bí àbíkẹ́yìn yín ba ba yín wá Nígbà tí a padà lọ sọ́dọ̀ baba wa, tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ, a sọ ohun tí olúwa à mi wí fún un Nígbà náà ni baba wa wí pé, Ẹ padà lọ láti lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá Ṣùgbọ́n a wí pe, Àwa kò le è padà lọ, àyàfi bí àbúrò wa pátapáta yóò bá bá wa lọ A kò le è rí ojú ọkùnrin náà àyàfi tí àbúrò wa bá lọ pẹ̀lú wa Baba mi, ìránṣẹ́ rẹ wí fún wa pé, Ẹ mọ̀ pé ìyàwó mi bí ọmọkùnrin méjì fún mi Ọ̀kan nínú wọn lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, mo sì wí pé, Dájúdájú a ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ N kò sì tí ì ri láti ọjọ́ náà Tí ẹ bá tún mú èyí lọ, kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ohunkóhun bá ṣe é, ìbànújẹ́ ni ẹ ó fi mú ewú-orí mi lọ sí ipò òkú Nítorí náà, bí a bá padà tọ baba wa lọ láì sí ọmọ náà pẹ̀lú wa-nígbà tí a mọ̀ pé, ọmọ náà ni ẹ̀mí baba wa Tí ó bá ri pé ọmọkùnrin náà kò wá pẹ̀lú wa, yóò kú Àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò wá mú baba wa t'òun ti ewú orí lọ sí ipò òkú ní ìbànújẹ́ Ìránṣẹ́ rẹ ló ṣe onídùúró fún ààbò ọmọ náà lọ́dọ̀ baba mi Mo wí pé, Bí n kò bá mú-un padà tọ̀ ọ́ wá, baba mi, èmi ọ́ ru ẹ̀bi rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé mi! Nítorí náà, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó dúró ní ìhín lọ́dọ̀ olúwa à mi bí ẹrú dípò ọmọ náà Kí ọmọ náà bá àwọn arákùnrin rẹ̀ padà Báwo ni mo ṣe lè padà tọ baba mi lọ láì bá ṣe pé ọmọ náà wà pẹ̀lú mi Rárá, mi ò fẹ́ kí n rí ìbànújẹ́ tí yóò dé bá baba mi Jóṣẹ́fù Fi Ara Rẹ̀ Hàn Fún Àwọn Arákùnrin Rẹ̀ Jósẹ́fù kò sì le è pa á mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn tí ó dúró tì í Ó sì sunkún sókè tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn tí ó wà ní àyíká gbọ́ ohun ẹkún rẹ̀ Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kúrò ní ọ̀dọ̀ mi Kò sì sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀ Ó sì sunkún sókè kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Éjíbítì gbọ́ ohùn ẹkún rẹ̀, àwọn ilé Fáráò pẹ̀lú sì gbọ́ nípa rẹ̀ Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, Èmi ni Jósẹ́fù! Ṣe baba mi sì wà láàyè Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò le è dá a lóhùn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n níwájú rẹ̀ Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé, Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín tí ẹ tà sí ilẹ̀ Éjíbítì! Ṣùgbọ́n báyìí, Ẹ má ṣe banújẹ́, ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín ní títà tí ẹ tà mí sí ìhín, nítorí, ọ̀nà àti gba ẹ̀mí yín là ni Ọlọ́run ṣe rán mi sí ìhín ṣáájú yín Ìyàn tí ó ti mú láti ọdún méjì sẹ́yìn yìí yóò tẹ̀ ṣíwájú fún ọdún márùn ún sí i nínú èyí tí ẹnikẹ́ni kò ní gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ni kórè Ṣùgbọ́n Ọlọ́run rán mi ṣáájú yín sí ìhín láti da irú ọmọ yín sí fún-un yín lórí ilẹ̀ ayé àti láti fi ìgbàlà ńlá gba ẹ̀mí yín là Nítorí náà kì í ṣe ẹ̀yin ni ó rán mi wá sí ìhín bí kò ṣe Ọlọ́run Ó fi mí ṣe baba fún Fáráò, alákóso fún gbogbo ilé Fáráò àti alábojútó gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì Nísinsìn yìí, ẹ yára padà sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ sì wí fun un pé, èyí ni ohun tí Jósẹ́fù ọmọ rẹ wí, Ọlọ́run ti fi mí ṣe àkóso fún gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, ẹ sọ̀kalẹ̀ wá láì jáfara Ìwọ yóò gbé ní agbégbé Gósénì, ìwọ kì yóò jìnnà sí mi-ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ àti agbo màlúù rẹ àti gbogbo ohun tí ìwọ ní Èmi yóò pèṣè fún yín níbẹ̀ Nítorí ó sì ku ọdún márùn ún gbáko ti ìyàn yóò fi mú Kí ìwọ àti ilé rẹ àti ohun tí í ṣe tìrẹ má baà di aláìní Ẹ̀yin fúnra yín àti Bẹ́ńjámínì arákùnrin mi pẹ̀lú rí i pé, lóòótọ́ lóòótọ́, èmi Jósẹ́fù ni mo ń bá a yín sọ̀rọ̀ Ẹ sọ fún baba mi nípa gbogbo ọlá tí a fún mi ní ilẹ̀ Éjíbítì àti ohun gbogbo tí ẹ̀yin ti rí, kí ẹ sì mú baba mi tọ̀ mí wá sí ìhín yìí kíákíá Nígbà náà ni ó dì mọ́ Bẹ́ńjámínì arákùnrin rẹ̀, ó sì sunkún, Bẹ́ńjámínì náà sì dì mọ́ ọn, pẹ̀lú omijé lójú Ó sì tún fẹnu ko gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu, ó sì sunkún sí wọn lára Lẹ́yìn èyí, Jósẹ́fù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ Nígbà tí ìròyìn náà dé ààfin Fáráò pé àwọn arákùnrin Jósẹ́fù dé, inú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ dùn Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé, Wí fún àwọn arákùnrin rẹ pé, Èyí ni kí ẹ ṣe Ẹ di ẹrù lé ẹranko yín kí ẹ sì padà sí ilẹ̀ Kénánì, kí ẹ sì mú baba yín àti ìdílé yín tọ̀ mí wá Èmi yóò fún un yín ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Éjíbítì, ẹ̀yin yóò sì le è gbádùn ilẹ̀ yìí A pàṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn pé, Ẹ ṣe èyí Ẹ mú kẹ̀kẹ́ ẹrù láti ilẹ̀ Éjíbítì fún àwọn ọmọ yín àti àwọn aya yín Kí ẹ sì mú baba yín tọ mí wá Ẹ má ṣe àníyàn nípa ohun-ìní yín nítorí èyí tí ó dára jù nínú ilẹ̀ Éjíbítì yóò jẹ́ tiyín   Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe èyí Jósẹ́fù fún wọn ni kẹ̀kẹ́ ẹrù bí Fáráò ti pàṣẹ, ó sì fún wọn ní oúnjẹ fún ìrìn-àjò wọn pẹ́lú Ó fún ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ tuntun Ṣùgbọ́n Bẹ́ńjámínì ni ó fún ní ọ̀ọ́dúnrún ẹyọ owó idẹ fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ márùn ún Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó ránṣẹ́ sí baba rẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru àwọn ohun mèremère ilẹ̀ Éjíbítì àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ọkà àti oríṣìíríṣìí oúnjẹ Nígbà náà ni ó rán àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, bí wọ́n ṣe ń pínyà, ó wí fún wọn pé, Ẹ má ṣe jà ní ọ̀nà o! Báyìí ni wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì wá sí ọ̀dọ̀ Jákọ́bù baba wọn ní ilẹ̀ Kénánì Wọn wí fún un pé, Jósẹ́fù sì wà láàyè! Kódà òun ni alákòóṣo ilẹ̀ Éjíbítì Ẹnu ya Jákọ́bù, kò sì gbà wọ́n gbọ́ Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun gbogbo tí Jósẹ́fù ti sọ fún wọn fún un tí ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Jósẹ́fù fi ránṣẹ́ láti gbé e padà wá, iyè Jákọ́bù, baba wọn ṣọ Ísírẹ́lì sì wí pé, Mo gbà dájúdájú wí pé, Jósẹ́fù ọmọ mi wà láàyè Èmi ó lọ rí i kí n tó kú Jákọ́bù lọ sí Éjíbítì Báyìí ni Ísírẹ́lì mú ìrìn-àjò rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ní, nígbà tí ó sì dé Báá-Ṣébà, ó rúbọ sí Ọlọ́run Ísáákì baba rẹ̀ Ọlọ́run sì bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ ní ojú ìrán ní òru pé, Jákọ́bù! Jákọ́bù! Ó sì dáhùn pé, Èmi nìyí Ọlọ́run sì wí pé, Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá níbẹ̀ Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Éjíbítì, èmi yóò sì tún mú ọ pada wá Ọwọ́ Jósẹ́fù fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí Nígbà náà ni Jákọ́bù kúrò ní Báá-Ṣébà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì mú Jákọ́bù bàbá wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Fáráò fí ránsẹ́ fún ìrìn-àjò rẹ̀ Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun-ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kénánì, Jákọ́bù àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ obìnrin-gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Éjíbítì Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Éjíbítì Rúbẹ́nì àkọ́bí Jákọ́bù Àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì Ánókù, Pálù, Ésírónì àti Kámì Àwọn ọmọkùnrin Símónì Jémúélì, Jámínì, Óhádì, Jákínì, Ṣóhárì àti Ṣáúlì, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kénánì Àwọn ọmọkùnrin Léfì Gáṣónì, Kóhátì àti Mérárì Àwọn ọmọkùnrin Júdà Ẹ́rì, Ónánì, Ṣélà, Pérésì àti Ṣérà Àwọn ọmọ Pérésì Ésírónì àti Ámúlù Àwọn ọmọkùnrin Ísákárì! Tólà, Pútà, Jásíbù àti Ṣímírónì Àwọn ọmọkùnrin Ṣébúlúnì Ṣérédì, Élónì àti Jáhálélì Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Líà tí ó bí fún Jákọ́bù ní Padani-Árámù yàtọ̀ fún Dínà ọmọbìnrin rẹ̀ Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́talélọ́gbọ̀n lápapọ̀ Àwọn ọmọkùnrin Gádì, Ṣífónì, Ágì, Ṣúnì, Ésíbónì, Érì, Áródì, àti Árélì Àwọn ọmọkùnrin Ásérì Ímínà, Íṣífà, Íṣífì àti Béríà Arábìnrin wọn ni Ṣérà Àwọn ọmọkùnrin Béríà Ébérì àti Málíkíélì Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Jákọ́bù bí nípaṣẹ̀ Ṣílípà, ẹni tí Lábánì fi fún Líà ọmọbìnrin rẹ̀ Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún lápapọ̀ Àwọn ọmọkùnrin Rákélì aya Jákọ́bù Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì Ní Éjíbiti, Áṣénátù ọmọbìnrin Pọ́tíférà, alábojútó àti àlùfáà Ónì, bí Mánásè àti Éfúráímù fún Jósẹ́fù Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì Bélà, Békérì, Áṣíbélì, Gérà, Náámánì, Éhì, Rósì, Múpímù, Húpímù àti Árídà Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Rákẹ́lì bí fún Jákọ́bù Wọ́n jẹ́ mẹ́rìnlá lápapọ̀ Àwọn ọmọ Dánì Úsímù Àwọn ọmọ Náfítalì Jáháṣíè, Gúnì, Jésérì, àti Ṣílémù Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Bílíhà ẹni tí Lábánì fi fún Rákélì ọmọ rẹ̀ bí fún Jákọ́bù Wọ́n jẹ́ méje lápapọ̀ Gbogbo àwọn tí ó lọ pẹ̀lú Jákọ́bù sí Éjíbítì, àwọn tí ó jẹ́ ìran rẹ̀ tààrà láì ka àwọn aya ọmọ rẹ̀, jẹ́ ènìyàn mẹ́rìndín-ní-àadọ́rin Pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin méjì tí a bí fún Jósẹ́fù ní Éjíbítì àwọn ará ilé Jákọ́bù tí ó lọ sí Éjíbítì jẹ́ àádọ́rin lápapọ̀ Jákọ́bù sì rán Júdà ṣáájú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Jósẹ́fù, kí wọn báà le mọ ọ̀nà Gósénì Nígbà tí wọ́n dé agbégbé Gósénì, Jósẹ́fù tọ́jú kẹ̀kẹ́-ẹsin rẹ̀ ó sì lọ sí Gósénì láti pàdé Ísírẹ́lì baba rẹ̀ Bí Jósẹ́fù ti dé iwájú baba rẹ̀, ó dì mọ́ baba rẹ̀ ó sì sunkún fún ìgbà pípẹ́ Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé, Wàyí o, mo le kú, níwọ̀n bí mo ti rí i fún ara a mi pé, o wà láàyè ṣíbẹ̀ Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti fún àwọn ará ilé baba rẹ̀ pé, Èmi yóò gòkè lọ, èmi yóò sì bá Fáráò sọ̀rọ̀, èmi yóò sì wí fún-un pé, Àwọn arákùnrin mi àti ìdílé baba mi tí ń gbé ní Kénánì ti tọ̀ mí wá Darandaran ni àwọn ènìyàn náà, wọ́n ń tọ́jú ẹran-ọ̀sìn, wọ́n sì kó agbo ẹran wọn àti agbo màlúù wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú wá Nígbà tí Fáráò bá pè yín wọlé tí ó sí béèrè irú iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe, ẹ fún-un lésì pé, àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń tọ́jú ẹran-ọ̀sìn ni láti ìgbà ewe wa wá gẹ́gẹ́ bí a ṣe ba a lọ́wọ́ àwọn baba wa Nígbà náà ni wọn yóò fún un yín láàyè láti tẹ̀dó sí ilẹ̀ Gósénì Nítorí pé àwọn ará Éjíbítì kóríra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ darandaran Jóṣẹ́fù àti ìyàn ní ilẹ̀ Éjíbítì Jósẹ́fù lọ sọ fún Fáráò pé, Baba mi àti àwọn arákùnrin mi, pẹ̀lú agbo ẹran, agbo màlúù àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, ti dé láti ilẹ̀ Kénánì, wọ́n sì ti wà ní ilẹ̀ Gósénì báyìí Ó yan márùn-ún àwọn arákùnrin rẹ́, ó sì fi wọ́n han Fáráò Fáráò béèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, Kín ni iṣẹ́ yín Wọ́n sì fèsì pé, Darandaran ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti jẹ́ darandaran Wọ́n sì tún sọ fun un síwájú sí i pé, A wá láti gbé ìhín yìí fún ìgbà díẹ̀ nítorí ìyàn náà mú púpọ̀ ní ilẹ̀ Kénánì, àwọn ohun-ọ̀sìn àwa ìránṣẹ́ rẹ kò sì rí ewéko jẹ Nítorí náà jọ̀wọ́ má sàì jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tẹ̀dó sí ilẹ̀ Gósénì Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé, Baba rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ tọ̀ ọ́ wá, Ilẹ̀ Éjíbítì sì nìyí níwájú rẹ Mú àwọn arákùnrin rẹ tẹ̀dó sí ibi tí ó dára jù nínú ilẹ̀ náà Jẹ́ kí wọn máa gbé ní Gósénì Bí o bá sì mọ ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó ní ẹ̀bùn-ìtọ́jú ẹran, fi wọ́n ṣe olùtọ́jú ẹran-ọ̀sìn mi Nígbà náà ni Jósẹ́fù mú Jákọ́bù baba rẹ̀ wọlé wá sí iwájú Fáráò Lẹ́yìn ìgbà tí Jákọ́bù súre fún Fáráò tán Fáráò béèrè pé, Ọmọ ọdún mélòó ni ọ́ Jákọ́bù sì dá Fáráò lóhùn, Ọdún ìrìn-àjò ayé mi jẹ́ àádóje , ọjọ́ mi kò pọ̀, ó sì kún fún wàhálà, ṣíbẹ̀ kò ì tí ì tó ti àwọn baba mi Nígbà náà ni Jákọ́bù tún súre fún Fáráò, ó sì jáde lọ kúrò níwájú rẹ̀ Joṣẹ́fù sì fi baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sí ilẹ̀ Éjíbítì, ó sì fún wọn ní ohun-ìní ní ibi tí ó dára jù ní ilẹ̀ náà, ní agbégbé Ráméṣéṣì bí Fáráò ti pàṣẹ Jósẹ́fù sì pèṣè oúnjẹ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi iye àwọn ọmọ wọn Ṣùgbọ́n kò sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ náà nítorí tí ìyàn náà mú púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ Éjíbítì àti ilẹ̀ Kénánì gbẹ nítorí ìyàn náà Jósẹ́fù gba gbogbo owó tí ó wà ní ilẹ̀ Éjíbítì àti Kénánì ní ìpààrọ̀ fún ti ọkà tí wọn ń rà, ó sì mú owó náà wá sí ààfin Fáráò Nígbà tí owó wọn tán pátapáta ní Éjíbítì àti Kénánì, gbogbo Éjíbítì wá bá Jósẹ́fù, wọ́n wí pé, Fún wa ní oúnjẹ, èéṣe tí a ó fi kú ní ojú rẹ Gbogbo owó wa ni a ti ná tan Jósẹ́fù wí pé, Ẹ mú àwọn ẹran-ọ̀sìn yín wá, èmi yóò fún un yín ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran-ọ̀sìn yín, níwọ̀n bí owó yín ti tan Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn tọ Jósẹ́fù wá, ó sì fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹsin, àgùntàn, ewúrẹ́, màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn Ó sì mú wọn la ọdún náà já, tí ó ń fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran-ọ̀sìn wọn Nígbà tí ọdún náà parí, wọn padà tọ̀ ọ́ wá ní ọdún tí ó tẹ̀le, wọn wí pé, A kò le fi pamọ́ fun olúwa wa pé níwọ̀n bí owó wa ti tan tí gbogbo ẹran-ọ̀sìn wa sì ti di tirẹ̀ pé, kò sí ohunkóhun tó kù fún olúwa wa bí kò ṣe ara wa àti ilẹ̀ wa Èése tí àwa yóò fi parun lójú rẹ, ra àwa tìkárawa àti ilẹ̀ wa ní ìpààrọ̀ fún oúnjẹ, àwa àti ilẹ̀ wa yóò sì wà nínú ìgbékùn Fáráò Fún wa ni oúnjẹ kí àwa kí ó má ba à kú, kí ilẹ̀ wa má ba à di ahoro Nítorí náà Jósẹ́fù ra gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní Éjíbítì fún Fáráò, kò sí ẹnìkan tí ó sẹ́kù ní Éjíbítì tí kò ta ilẹ̀ tirẹ̀ nítorí ìyàn náà mú jù fún wọn Gbogbo ilẹ̀ náà sì di ti Fáráò, Jósẹ́fù sì sọ gbogbo ará Éjíbítì di ẹrú láti igun kan dé èkejì Ṣùgbọ́n sá, kò ra ilẹ̀ àwọn àlùfáà, nítorí wọ́n ń gba ìpín oúnjẹ lọ́wọ́ Fáráò, wọn sì ní oúnjẹ tí ó tó láti inú ìpín tí Fáráò ń fún wọn Ìdí nìyí tí wọn kò fi ta ilẹ̀ wọn Jósẹ́fù wí fún àwọn ènìyàn náà pé, Níwọ̀n ìgbà tí mo ti ra ẹ̀yin àti ilẹ̀ yín tan lónìí fún Fáráò, irúgbìn rè é, ẹ lọ gbìn ín sí ilẹ̀ náà Ṣùgbọ́n nígbà tí ire oko náà bá jáde, ẹ ó mú ìdá kan nínú ìdá márùn-ún rẹ̀ fún Fáráò Ẹ le pa ìdá mẹ́rin tókù mọ́ fún ara yín àti ìdílé yín àti àwọn ọmọ yín Wọ́n dá á lóhùn pé, O ti gbà wá là, Ǹjẹ́ kí a rí ojúrere níwájú olúwa wa, àwa yóò di ẹrú Fáráò Nítorí náà Jósẹ́fù sọ ọ́ di òfin nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ni Éjíbítì, ó sì wà bẹ́ẹ̀ di òni olónìí-pé, ìdá kan nínú ìdá márùn-ún irè oko jẹ́ ti Fáráò, ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò di ti Fáráò Àwọn ará Ísírẹ́lì sì tẹ̀dó sí Éjíbítì ní agbégbé Gósénì Wọ́n ní ohun-ìní fún ara wọn, wọ́n sì bí sí i tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n pọ̀ si gidigidi ní iye Jákọ́bù gbé ní Éjíbítì fún ọdún mẹ́tadínlógún iye ọdún ọjọ́ ayé rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tàdín ní àádọ́jọ Nígbà tí àkókò ń súnmọ́ etílé fún Ísírẹ́lì láti kú, ó pe Jósẹ́fù, ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún-un pé, Bí mo bá rí ojú rere ni oju rẹ̀ fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi, kí o sì ṣe ìlérí pé ìwọ yóò fi àánú àti òtítọ́ hàn sí mi Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Éjíbítì, Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo bá sinmi pẹ̀lú àwọn baba mi, gbé mí jáde kúrò ní Éjíbítì kí o sì sin mí sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba mi sí Jóṣẹ́fù sì dáhùn wí pé, Èmi ó ṣe bí ìwọ ti wí Jákọ́bù wí pé, Búra fún mi, Jósẹ́fù sì búra fún un Ísírẹ́lì sì tẹ orí rẹ̀ ba, bí ó ti sinmi lé ori ìbùsùn rẹ̀ Mánásè àti Éfúráímù Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ si, a wí fún Jósẹ́fù pé, Baba rẹ ń sàìsàn, nítorí náà, ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Mánásè àti Éfúráímù lọ́wọ́ lọ pẹ̀lú rẹ̀ Nígbà tí a sọ fún Jákọ́bù pé, Jósẹ́fù ọmọ rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, Ísírẹ́lì rọ́jú dìde jókòó lórí ìbùsùn rẹ̀ Jákọ́bù wí fún Jósẹ́fù pé, Ọlọ́run Olódùmarè fara hàn mí ní Lúsì ní ilẹ̀ Kénánì, níbẹ̀ ni ó sì ti súre fún mi Ó sì wí fún mi pé, Èmi yóò mú kí bí sí i, ìwọ yóò sì pọ̀ sí i, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá, Èmi yóò sì fún ìwọ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní ayérayé Nítorí náà báyìí, àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí a bí fún ọ ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí èmi kí ó tó tọ̀ ọ́ wá ní ìhín, ni mo sọ di ọmọ mi fúnra mi Mánásè àti Éfúráímù yóò jẹ́ tèmi gẹ́gẹ́ bí Rúbẹ́nì àti Símónì ti jẹ́ tèmi Àwọn ọmọ mìíràn tí ìwọ bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ ọmọ rẹ Ní ilẹ̀ tí wọn yóò jógún, orúkọ arákùnrin wọn ni a ó máa fi pè wọ́n Bí mo ti ń padà láti Pádánì, Rákélì kú ní ọ̀nà nígbà tí ó sì wà ní ilẹ̀ Kénánì, èyí tó mú ìbànújẹ́ bá mi, ní bi tí kò jìnnà sí Éfúrátì Nítorí náà èmí sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà tí ó lọ sí Éfúrátì Nígbà tí Ísírẹ́lì rí àwọn ọmọ Jósẹ́fù, ó béèrè wí pé, Àwọn wo nìyí Jósẹ́fù fún baba rẹ̀ lésì pé, Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi fún mi ní ìhín Nígbà náà ni Ísírẹ́lì wí pé, Kó wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi kí èmi kí ó baà le súre fún wọn Báyìí, ojú Ísírẹ́lì ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran Jósẹ́fù sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnu kò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé, Èmi kò lérò rárá pé, mo tún le rí ojú rẹ mọ́ láéláé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún fún mi ní àǹfààní, mo sì tún rí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú Nígbà náà ni Jósẹ́fù kó àwọn ọmọ náà kúrò ní orí eékún baba rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì tẹ́ríba Jósẹ́fù sì mú àwọn méjèèjì, Éfúráímù ni o fi sí ọwọ́ ọ̀tún òun tìkararẹ̀, èyí tí í ṣe ọwọ́ òsì fún Ísírẹ́lì, ó sì fi Mánásè sí ọwọ́ òsì ara rẹ̀, èyí tí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún Ísírẹ́lì Ísírẹ́lì sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jáde, ó sì gbe lé Éfúráímù lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ tàṣé ara wọn, ó sì na ọwọ́ òsì lé Mánásè lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Mánásè ni àkọ́bí Nígbà náà ni ó súre fún Jósẹ́fù wí pé, Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run, ẹni tí baba mi Ábúráhámù àti Ísáákì rìn níwájú Rẹ̀, Ọlọ́run tí ó ti jẹ́ olùtọ́jú àti aláàbò mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní, Ańgẹ́lì tí ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu, kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí Kí a máa fi orúkọ́ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba mi Ábúráhámù àti Ísáákì, kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé Nígbà tí Jósẹ́fù rí i pé baba òun gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Éfúráímù lórí, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì gbá ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lórí Éfúráímù lọ sí orí Mánásè Jósẹ́fù wí fun pé, Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀ Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé, Ní orúkọ yín ni Ísírẹ́lì yóò máa súre yìí pé Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Éfúráímù àti Mánásè   Nígbà náà ni Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé, Ọjọ́ ikú mi súnmọ́ etílé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú yín, yóò sì mú un yín padà sí ilẹ̀ àwọn baba yín Pẹ̀lúpẹ̀lú èmi yóò fún ọ ní ìpín kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ Ilẹ̀ tí mo fi idà àti ọ̀kọ̀ mi gbà lọ́wọ́ àwọn ará Ámórì Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Jákọ́bù Sí Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Nígbà náà ni Jákọ́bù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì wí pé, Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí n le è sọ ohun tí yóò sẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú fún-un yín Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí ẹ sì tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ Jákọ́bù Ẹ fetí sí Ísírẹ́lì baba yín Rúbẹ́nì, ìwọ ni àkọ́bí mi, agbára mi, ìpìlẹṣẹ̀ ipá mi, títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára Ẹni ríru bí omi òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́, nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ, lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́ Símónì àti Léfì jẹ́ arákùnrin— idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn, kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn, nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn, wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ó gbóná púpọ̀, àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà Èmi yóò tú wọn ká ní Jákọ́bù, èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Ísírẹ́lì Júdà, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ, ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀ta rẹ, àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ Ọmọ kìnnìún ni ọ́, ìwọ Júdà, o darí láti ìgbẹ́ ọdẹ, ọmọ mi Bí i kìnnìún, o ba mọ́lẹ̀, o sì sùn sílẹ̀ bí i abo kìnnìún, Ta ni ó tó bẹ́ẹ̀, kí o lé e dìde Ọ̀pá oyè kì yóò kúrò ní Júdà bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìsàkóso kì yóò kúrò láàrin ẹṣẹ̀ rẹ̀, títí tí ẹni tí ó ni í yóò fi dé, tí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè yóò máa wárí fún un Yóò má ṣo ọmọ ẹsin rẹ̀ mọ́ igi àjàrà àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ẹ̀ka tí ó dára jù Yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì àti ẹ̀wù rẹ̀ nù nínú omi-pupa ti eṣo àjàrà Ojú rẹ̀ yóò rẹ̀ dòdò ju wáìnì lọ, ẹyín rẹ yóò sì funfunu pẹ̀lú omi-ọyàn Ṣébúlúnì yóò máa gbé ní etí òkun, yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi, agbégbé rẹ yóò tàn ká títí dé Ṣídónì Ísákárì jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ alágbára tí ó sùn sílẹ̀ láàrin àpò ẹrù méjì Nígbà tí ó bá rí bí ibi ìsinmi òun ti dára tó, àti bí ilẹ̀ rẹ̀ ti ní ìdẹ̀ra tó, yóò tẹ èjìká rẹ̀ ba láti ru àjàgà, yóò sì fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ipá Dánì yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì Dánì yóò jẹ́ ejo ni pópónà àti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà, tí ó bu ẹsin jẹ ní ẹṣẹ̀, kí ẹni tí n gùn-un bá à le è subú sẹ́yìn Mo ń dúró de ìtúsilẹ̀ rẹ, Olúwa Ẹgbẹ́-ogun àwọn ẹlẹ́sin yóò kọ lu Gádì, ṣùgbọ́n yóò kọ lu wọ́n ní gìgíṣẹ̀ wọn Oúnjẹ Áṣérì yóò dára yóò ṣe àṣè tí ó yẹ fún ọba Náfútalì yóò jẹ́ abo àgbọ̀nrín tí a tú sílẹ̀ tí ó ń bí ọmọ daradara Jóṣẹ́fù jẹ́ àjàrà eléṣo, àjàrà eléṣo ní etí odò, tí ẹ̀ka rẹ̀ gun orí odi Pẹ̀lú ìkorò, àwọn tafàtafà dojú ìjà kọ ọ́, wọ́n tafà sí í pẹ̀lú ìkanra, Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára, ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le, nítorí ọwọ́ alágbára Jákọ́bù, nítorí olútọ́jú àti aláàbò àpáta Ísírẹ́lì Nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́, nítorí Olódùmarè tí ó bù kún ọ, pẹ̀lú láti ọ̀run wá, ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìṣàlẹ̀, ìbùkún ti ọmú àti ti inú, ìbùkún baba rẹ pọ̀ púpọ̀ ju ìbùkún àwọn òkè ńlá ìgbàanì, ju ẹ̀bùn ńlá àwọn òkè láéláé Jẹ́ kí gbogbo èyí sọ̀kalẹ̀ sí orí Jóṣẹ́fù, lé ìpéǹpéjú ọmọ aládé láàrin arákùnrin rẹ̀ Bẹ́ńjámínì jẹ́ ìkookò tí ó burú Ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran-ọdẹ rẹ, ní àsáálẹ́, ó pín ìkógun Gbogbo ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá, èyí sì ni ohun tí baba wọn sọ fún wọn nígbà tí ó súre fún wọn, tí ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìbùkún tí ó tọ́ sí i Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́fẹ́ Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hítì ará Éfúrónì Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Mákípélà, nítòsí Mámúrè ní Kénánì, èyí tí Ábúráhámù rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀-ìsìnkú lọ́wọ́ Éfúrónì ará Hétì pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀ Níbẹ̀ ni a sin Ábúráhámù àti aya rẹ̀ Ṣárà sí, níbẹ̀ ni a sin Ísáákì àti Rèbékà aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Líà sí Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni a rà lọ́wọ́ ará Hítì Nígbà tí Jákọ́bù ti pàṣẹ yìí fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó gbé ẹṣẹ rẹ̀ sókè sórí ibùsùn, ó sì kú, a sì ko jọ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ Ìran Ádámù títí dé ìran Nóà Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Ádámù Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ó dá a ní àwòrán Ọlọ́run Ó dá wọn ní akọ àti abo, ó sì súre fún wọn Nígbà tí ó dá wọn tan ó pè wọ́n ní ènìyàn Nígbà tí Ádámù di ẹni Àádóje ọdún , ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣétì Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Ṣétì, ó tún wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún , ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Àpapọ̀ ọdún tí Ádámù gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-ọgbọ̀n , ó sì kú Nígbà tí Ṣétì pé àrùnlélọ́gọ́rùn ún ọdún , ó bí Énọ́sì Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Énọ́sì, ó sì gbé fún ẹgbẹ̀rin-ó-lé-méje ọdún , ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Àpapọ̀ ọdún Ṣẹ́tì sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-méjìlá , ó sì kú Nígbà tí Énọ́sì di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Kénánì Lẹ́yìn tí ó bí Kénánì, ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin-ọdún-ó-lé-mẹ́ẹ̀dógún , ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin Àpapọ̀ ọdún Énọ́sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-márùn-ún , ó sì kú Nígbà tí Kénánì di àádọ́rin ọdún ni ó bí Máhálálélì Lẹ́yìn tí ó bí Máhálálélì, ó wà láàyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rín ọdún , ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbínrin Àpapọ̀ ọjọ́ rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ó-lé-mẹ́wàá ọdún , ó sì kú Nígbà tí Máhálálélì pé ọmọ àrúnlélọ́gọ́ta ọdún ni ó bí Járédì Máhálálélì sì gbé fún ẹgbẹ̀rin-ó-lé-ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Járédì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Àpapọ̀ iye ọdún rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-márùn-ún , ó sì kú Nígbà tí Járédì pé ọmọ ọgọ́jọ-ó-lé-méjì ọdún ni ó bí Énọ́kù Lẹ́yìn èyí, ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó sì bí àwọn ọmọkúnrin àti ọmọbìnrin Àpapọ̀ ọdún rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-méjìdínlógójì ó sì kú Nígbà tí Énọ́kù pé ọmọ ọgọ́ta-ó-lé-márùn ọdún ni ó bí Mètúsẹ́là Lẹ́yìn tí ó bí Mètúsẹ́là, Énọ́kù sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún , ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Àpapọ̀ ọjọ́ Énọ́kù sì jẹ́ irínwó-dín-márùndínlógójì-ọdún Énọ́kù bá Ọlọ́run rìn a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ Nígbà tí Mètúsẹ́là pé igba-ó-dín-mẹ́talá ọdún ní o bí Lámékì Lẹ́yìn èyí ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin-dín-méjìdínlógún ọdún , ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Àpapọ̀ ọdún Mètúsẹ́là jẹ́ ẹgbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-mọ́kànlélọ́gbọ̀n , ó sì kú Nígbà tí Lámékì pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án ni ó bí ọmọkùnrin kan Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Nóà, ó sì wí pé, Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi gégùn-ún Lẹ́yìn tí ó bí Nóà, Lámékì gbé fún ẹgbẹ̀ta-ó-dín-márùn-ún ọdún , ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Àpapọ̀ ọdún rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin-ọdún-ó-dín-mẹ́talélógún , ó sì kú Lẹ́yìn tí Nóà pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ni ó bí Ṣémù, Ámù àti Jáfétì Jósẹ́fù Fi Ọkàn Àwọn Arákùnrin Rẹ̀ Balẹ̀ Jósẹ́fù sì subú lé baba rẹ̀, ó sunkún, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnu Nígbà náà ni Jósẹ́fù pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Ísírẹ́lì baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀, Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú Àwọn ará Éjíbítì sì sọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́ Nígbà tí ọjọ́ ìṣọ̀fọ̀ náà kọjá Jósẹ́fù wí fún àwọn ará ilé Fáráò pé, Bí mo bá bá ojúrere yín pàdé, ẹ bámi sọ fún Fáráò Baba mi mú mi búra ó sì wí fún mi pé, Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú sin mi sínú ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kénánì Nísinsin yìí, jẹ́ kí n lọ kí n sì sìnkú baba mi, lẹ́yìn náà èmi yóò padà wa   Fáráò wí pé, Gòkè lọ, kí o sì sin baba rẹ, bí ó tí mú ọ búra Báyìí ni Jósẹ́fù gòkè lọ láti sìnkú baba rẹ̀ Gbogbo àwọn ìjòyè Fáráò ni ó sìn ín lọ—àwọn ènìyàn pàtàkì pàtàkì ilé rẹ̀, àti àwọn ènìyàn pàtàkì pàtàkì ilẹ̀ Éjíbítì Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn ará ilé Jóṣẹ́fù àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ ilé baba rẹ̀, àwọn ọmọ wọn nìkan àti agbo ẹran pẹ̀lú agbo màlúù ni ó sẹ́ kù ní Gósénì Kẹ̀kẹ́ ẹsin àti àwọn ẹlẹ́sin pẹ̀lú gòkè lọ Àìmọye ènìyàn ni ó lọ Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ ìpakà Átadì, ní ẹ̀bá Jọ́dánì, wọn pohùn réré ẹkún Níbẹ̀ ni Jósẹ́fù sì tún dúró ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ méje Nígbà tí àwọn ará Kénánì tí ń gbé níbẹ̀ ri i bí wọ́n ti ń sọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Átadì, wọ́n wí pé, Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Éjíbítì ń ṣe yìí Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Mísíráímù Kò sì jìnnà sí Jọ́dánì Báyìí ni àwọn ọmọ Jákọ́bù ṣe ohun tí baba wọn páṣẹ fún wọn Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kénánì, wọ́n sì sin-ín sínú ihò àpáta tí ó wà ní oko Makipélà, ní tòsí i Mámúrè tí Ábúráhámù rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Éfúrónì ará Hítì, pẹ̀lú ilẹ̀ náà Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú baba rẹ̀ tan, Jóṣẹ́fù padà sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn mìíràn tí ó tẹ̀lé e lọ láti sin baba rẹ̀ Nígbà tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù rí i pé baba wọn kú, wọ́n wí fún ara wọn pé, Ǹjẹ́ bí ó bá ṣe pé Jósẹ́fù sì fi wá sínú ńkọ́, tí ó sì fẹ́ gbẹ̀ṣan gbogbo aburú tí a ti ṣe sí i Nítorí náà wọ́n ránṣẹ́ sí Jósẹ́fù wí pé, Baba rẹ fi àṣẹ yìí sílẹ̀ kí ó tó lọ wí pé Èyí ni kí ẹ̀yin kí ó sọ fún Jóṣẹ́fù Mo bẹ̀ ọ́ kí o dáríjìn àwọn arákùnrin rẹ, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti aburú tí wọ́n ṣe sí ọ, èyí tí ó mú ibi bá ọ Nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run baba rẹ jìn wọ́n Nígbà tí iṣẹ́ ti wọ́n rán dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Jósẹ́fù sunkún Àwọn arákùnrin rẹ̀ wá, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n wí pé, Ẹrú rẹ ni a jẹ́ Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù wí fún wọn pé, Ẹ má ṣe bẹ̀rù, èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run bí Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbérò láti ṣe mi ní ibi, ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbérò láti fi ṣe rere tí ń ṣe lọ́wọ́ yìí ni gbígba ẹ̀mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn là Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù Èmi yóò pèṣè fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín Ó tún fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fun wọn Jósẹ́fù sì ń gbé ní Éjíbítì pẹ̀lú gbogbo ìdílé baba rẹ̀ Ó sì wà láàyè fún àádọ́fà ọdún Ó sì rí ìran kẹta ọmọ Éfúrémù-Àwọn ọmọ Mákírì, ọmọkùnrin Mánásè ni a sì gbé le eékún Jósẹ́fù nígbà tí ó bí wọn Nígbà náà ni Jóṣẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, Mo ti fẹrẹ kú, ṣùgbọ́n dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, yóò sì mú-un yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí ó ti ṣèlérí ní ìbúra fún Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù Jóṣẹ́fù sì mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì búra májẹ̀mu kan wí pé, Dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, nígbà náà ni ẹ gbọdọ̀ kó egungun mi lọ́wọ́ kúrò ní ìhín Báyìí ni Jóṣẹ́fù kú nígbà tí ó pé àádọ́fà ọdún Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n se òkú rẹ̀ lọ́jọ̀ tan, a gbé e sí inú pósí ní Éjíbítì Ìkún omi Nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si ní orí ilẹ̀, wọ́n sí i bí àwọn ọmọbìnrin Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya Nígbà náà ni Olúwa wí pé, Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran ara ṣáà ni òun, ọgọ́fà ọdún, ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ Àwọn òmìrán wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lò pọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà Olúwa sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo Inú Olúwa sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́ Nítorí náà, Olúwa wí pé Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn Ṣùgbọ́n, Nóà rí ojúrere Olúwa Wọ̀nyí ni ìtàn Nóà Nóà nìkan ni ó jẹ́ olóòótọ́ àti aláìlábùkù ní ìgbà ayé rẹ̀, ó sì bá Ọlọ́run rìn Nóà sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣémù, Ámù àti Jáfétì Ayé sì kún fún ìbàjẹ́ gidigidi ní ojú Ọlọ́run, ó sì kún fún ìwà ipá pẹ̀lú Ọlọ́run sì rí bí ayé ti bàjẹ́ tó, nítorí àwọn ènìyàn ayé ti bá ara wọn jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà wọn Ọlọ́run sì wí fún Nóà pé, Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípaṣẹ̀ wọn Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú Nítorí náà fi igi ọ̀mọ̀ kan ọkọ̀, kí o sì yọ yàrá sí inú rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ tinú-tẹ̀yìn Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà Gígùn rẹ̀ ní òòró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ Ṣe òrùlé sí orí ọkọ̀ náà ní ìgbọ̀nwọ́ kan, sì ṣe ọkọ̀ náà ní alájà mẹ́ta, ipá kan ní ìṣàlẹ̀, ọ̀kan ní àárin àti ọ̀kan tí ó kù ní òkè, ẹ̀gbẹ́ ni kí ó ṣe ẹnu ọ̀nà ọkọ̀ náà sí Èmi yóò mú ìkún omi wá sí ayé láti pa gbogbo ohun ẹlẹ́mìí run, lábẹ́ ọ̀run Gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè ní inú Gbogbo ohun tí ó wà nínú ayé yóò parun Ṣùgbọ́n èmi ó dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì wọ ọkọ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú aya rẹ Ìwọ yóò mú gbogbo ohun alààyè takọ tabo wá sí inú ọkọ̀ kí wọn le wà láàyè pẹ̀lú rẹ Mú onírúurú àwọn ẹyẹ, ẹranko àti àwọn ohun tí ń rákò ní méjìméjì kí a bá lè pa wọ́n mọ́ láàyè Mú onírúurú oúnjẹ wá sínú ọkọ̀ kí o pa wọ́n mọ́ fún jíjẹ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà nínú ọkọ̀ àti ènìyàn àti ẹranko Nóà sì ṣe ohun gbogbo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Nóà pé, Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí Mú méjeméje nínú àwọn ẹran tí ó mọ́, akọ àti abo, mú méjìméjì takọ tabo nínú àwọn ẹran aláìmọ́ Sì mú méjeméje pẹ̀lú nínú onírúurú ẹyẹ takọ tabo ni kí o mú wọn, wọlé sínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí á baà lè pa wọ́n mọ́ láàyè ní gbogbo ayé Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run, kúrò lórí ilẹ̀ Nóà sì ṣe ohun gbogbo tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un Nóà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún nígbà tí ìkún omi dé sórí ilẹ̀ Nóà àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì wọ inú ọkọ láti ṣá àsálà fún ìkún omi Méjìméjì ni àwọn ẹran tí ó jẹ́ mímọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà, akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Nóà sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Nóà Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kéjì, tí Nóà pé ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún, ni gbogbo ìṣun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì sí sílẹ̀ Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan-an ni Nóà àti Ṣémù, Ámù àti Jáfétì pẹ̀lú aya Nóà àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ Wọn mú ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn ní onírúurú wọn, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ẹyẹ àti àwọn ohun abìyẹ́ ni onírúurú wọn Méjìméjì ni gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè nínú wọlé pẹ̀lú Nóà sínú ọkọ̀ Gbogbo wọn wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Nóà, Olúwa sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀ Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi Omi náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó bo gbogbo àwọn òkè gíga tí ó wà lábẹ́ ọ̀run Omi náà kún bo àwọn òkè, bí ìwọ̀n mítà bí i méje Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a parẹ́ ènìyàn àti ẹranko, àwọn ohun tí ń rìn nílẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pátapáta ló ṣègbé Nóà àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ó ṣẹ́kù Omi náà sì bo ilẹ̀ fún àádọ́jọ ọjọ́ Ìkún omi fà Ọlọ́run sì rántí Nóà àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà Gbogbo ìṣun ibú àti fèrèsé ìṣàn ọ̀run tì, òjò pẹ̀lú sì dáwọ́ rírọ̀ dúró Omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, lẹ́yín àádọ́jọ ọjọ́, ó sì ti ń fà Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì ni ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ ṣórí òkè Árárátì Omi náà sì ń gbẹ si títí di oṣù kẹwàá Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹ́wàá, orí àwọn òkè sì farahàn Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Nóà sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀ Ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde, tí ó ń fò káàkiri síwá àti ṣẹ́yìn títí omi fi gbẹ kúrò ní orí ilẹ̀ Ó sì rán àdàbà kan jáde láti wò ó bóyá omi ti gbẹ kúrò lórí ilẹ̀ Ṣùgbọ́n àdàbà náà kò rí ìyàngbẹ ilẹ̀ bà lé nítorí omi kò tí ì tan lórí ilẹ̀, ó sì padà sọ́dọ̀ Nóà Nóà na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú ẹyẹ náà wọlé sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nínú ọkọ̀ Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀ Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àsáálẹ́, ó já ewé igi ólífì tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Nóà mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀ Nóà tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́ Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀ Nóà sì sí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ilẹ̀ ti gbẹ pátapáta Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Nóà pé Jáde kúrò nínú ọkọ̀, ìwọ àti aya rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ àti àwọn aya wọn Kó gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú rẹ jáde àwọn ẹyẹ, ẹranko àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀, kí wọn lè bí sí i, kí wọn sì pọ̀ sí i, kí wọn sì máa gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀ Nóà, àwọn ọmọ rẹ̀, aya rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì jáde Gbogbo àwọn ẹranko àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀ àti gbogbo ẹyẹ pátapáta ni ó jáde kúrò nínú ọkọ̀, ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ní irú tiwọn Nóà sì mọ pẹpẹ fún Olúwa , ó sì mú lára àwọn ẹran tí ó mọ́ àti ẹyẹ tí ó mọ́, ó sì fi rúbọ ṣísun lórí pẹpẹ Olúwa sì gbọ́ òórùn dídùn ó sì wí ní ọkàn rẹ̀ Èmi kì yóò tún fi ilẹ̀ ré nítorí ènìyàn mọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ ibi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, èmi kì yóò pa gbogbo ohun alààyè run mọ́ láé, bí mo ti ṣe Níwọ̀n ìgbà tí ayé bá sì wà, ìgbà ọ̀gbìn àti ìgbà ìkórè ìgbà òtútù àti ìgbà ooru, igbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òjò, ìgbà ọ̀ṣán àti ìgbà òru, yóò wà títí láé Májẹ̀mu Ọlọ́run Pẹ̀lú Nóà Ọlọ́run sì súre fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún aye Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀ àti gbogbo ẹja òkun a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́ Gbogbo ohun tó wà láàyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún-ún yín bí mo ṣe fi ewéko fún un yín, náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀ rẹ̀ A ó jẹ ẹnikẹ́ni tó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀ níyà Ikú ni yóò jẹ́ ìjìyà ìpànìyàn, ìbá à ṣe láti ọwọ́ ẹranko tàbí ènìyàn Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀ láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ Nítorí ní àwòrán Ọlọ́run ni Ọlọ́run dá ènìyàn Ṣùgbọ́n ní tiyín, ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ máa gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀, kí ẹ sì pọ̀ sí i lórí rẹ̀ Ọlọ́run sì wí fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín àti pẹ̀lú àwọn ìran yín tí ń bọ̀ lẹ́yìn Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbáà ṣe ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín, láéláé, Èmi kì yóò fi ìkún omi pa ayé run kúrò mọ láéláé, a kì yóò fi omi pa ayé run Ọlọ́run sì wí pé, Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrin èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀ Mo ti fi òṣùmàrè sí ojú ọ̀run, yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrin èmi àti ayé Nígbàkúgbà tí mo bá mú kí òjò sú, tí òṣùmàrè bá farahàn ní ojú ọ̀run Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrin èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run Nígbàkígbà tí òsùmàrè bá yọ ní ojú ọ̀run, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrin Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé Ọlọ́run sì wí fún Nóà pé, Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láàrin èmi àti gbogbo alààyè ní ayé Àwọn ọmọ Nóà tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣémù, Ámù àti Jáfétì Nípaṣẹ̀ àwọn ọmọ Nóà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni gbogbo ènìyàn ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé Nóà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà Ó mu àmupara nínú ọtí wáìnì àjàrà rẹ̀, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò, ó sì sùn nínú àgọ́ rẹ̀ Ámù tí í ṣe baba Kénání sì rí baba rẹ̀ ní ìhòòhò bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní ìta Ṣùgbọ́n Ṣémù àti Jáfétì mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòòhò baba wọn Wọ́n kọjú ṣẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòòhò baba wọn Nígbà tí ọtí dá kúrò ní ojú Nóà, tí ó sì mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ àti ohun tí Ámù ọmọ rẹ̀ ṣe sí i Ó wí pé Ègún ni fún Kénánì Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀ Ó sì tún wí pé Olùbùkún ni Olúwa , Ọlọ́run Ṣémù Kénánì yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣémù Ọlọ́run yóò mú Jáfétì gbilẹ̀, Jáfétì yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣémù Kénánì yóò sì jẹ́ ẹrú fún-un Nóà wà láàyè fún irínwó-ọdún-ó-dín-àádọ́ta lẹ́yìn ìkún omi Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Nóà jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-ní-àádọ́ta ọdún, ó sì kú Ìráhùn Hábákúkù Ìran tí wòlíì Hábákúkù rí Olúwa , emì yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́, Ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi Tàbí kígbe sí ọ ní ti, Ìwà ipá! ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédé Èéṣe tí ìwọ sì fààyè gba ìwà ìkà Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí, ìdájọ́ òdodo kò sì borí Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká, Nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà Ẹ wo ìnú àwọn aláìkọlà, ki ẹ sí wòye, Kí ìyàlẹnu kí o sí ṣe yin gidigidi Nítorí tí èmi yóò ṣe ohun kan ni òwúrọ̀ ọjọ́ ọ yín tí ẹ̀yin kì yóò sì gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé a sọ fún un yin Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Bábílónì dìde, àwọn aláìláàánú àti onínú fùfù ènìyàn tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe ti wọn Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà, ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn, Yóò máa ti inú wọn jáde Ẹ̀ṣin wọn yára ju ẹkùn lọ, wọ́n ṣì gbóná jú ìkókó àṣálẹ́ lọ àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká àwọn yóò sì wá láti ọ̀nà jínjìn réré, wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun Gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú wọn sì ko ìgbékùn jọ bí i yanrìn Wọn ó si máa fí àwọn ọba ṣẹ̀ṣín wọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìnín Nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà, yóò sì rékọjá, yóò siṣẹ̀ ní kika agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀ Olúwa , ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà Olúwa Ọlọ́run mi Ẹni mímọ mi, àwa kì yóò kú Olúwa , ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́ Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi ìwọ kò le gbà ìwà ìkà nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láàyè Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa ẹni tí i ṣe olododo ju wọn lọ run Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú òkun, bí àwọn ẹ̀dá inú òkun tí wọn ko ni alákòóso Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn ṣókè ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n-ńlá rẹ̀ nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú Nítorí náà, ó rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀, ó sì ń ṣun tùràrí fún àwọ̀n-ńlá rẹ̀ nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fí ń gbé ní ìgbádùn tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pá àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí, tí wọn yóò sí pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú Ìdáhùn Ọlọ́run Sí Ìráhùn Wòlíì Hábákúkù Èmi yóò dúró lórí ibùṣọ́ mi láti máa wòye Èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre Èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún nu àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí Nígbà náà ni Olúwa dáhun pé Kọ ìṣípayá náa sílẹ̀ kí o sí han ketekete lórí wàláà kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè yóò máa yára sí ìgbẹ̀yin kí yóò sí sọ èké bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́ Kíyèsí, ọkàn rẹ tí ó gbéga Ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n olododo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí-wáìnì ni ẹ̀tàn, agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmi ẹni tí ó sọ ìfá rẹ di gbígbòòrò bí ipò-òkú, ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀ ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé,  Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i! Tí ó sì ṣọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípaṣẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́ gbà! Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde lójijì Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò ha jí ni bi Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn Nítorí ìwọ tí ko orílẹ̀-èdè púpọ̀, àwọn ènìyàn tó kù yóò sì kó ọ nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ Ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀ Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀, tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga, kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi! Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mi rẹ Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá, àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú, tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé làálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún iná kí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún aṣán Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa , bí omi ṣe bo òkun Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì fí ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara, kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòòhò wọn Ìtì jú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú kí ìhòòhò rẹ kí ó lè hàn, aago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa , yóò yípadà sí ọ, ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ Nítorí ìwà-ipá tí ó tí hù sí Lébánónì yóò bò ọ́, àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀ ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ, ère dídá àti olùkọ́ èké Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnrarẹ̀ dá ó sì mọ ère tí kò le fọhùn Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, Wá ṣayé Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, Dìde Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà Góòlù àti sílífa ni a fi bò ó yíká kò sì sí èémí kan nínú rẹ Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹ́ḿpílì mímọ́ rẹ̀ Ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé pa rọ́rọ́ níwájú rẹ Àdúrà Hábákúkù Àdúrà wòlíì Hábákúkù gẹ́gẹ́ bí sígónótì Olúwa mo tí gbọ́ ohùn rẹ ẹrú sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ Olúwa ṣọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa, ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mímọ̀ ni ìbínú, rántí àánú Ọlọ́run yóò wa láti Témánì, Ibi mímọ́ jùlọ láti Òkè Páránì ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run, Ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ Dídán rẹ ṣí dàbí ìmọ́lẹ̀ Ìmọ́lẹ̀ kọ-ṣàn-án láti ọwọ́ rẹ wá, níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ ni iwájú rẹ ìyọnu ṣí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ Ó dúró, ó sì mi ayé ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì a sì tú àwọn òkè-ńlá ayérayé ká, àwọn òkè kéékèèkéé ayérayé sì tẹríba ọ̀nà rẹ ayérayé ni Mo rí àgọ́ Kúṣánì nínú ìpọ́njú àti àwọn ibùgbé Mídíanì nínú ìrora Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn Odò nì, Olúwa Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò síṣàn bí Ìbínú rẹ ha wá sórí òkun tí ìwọ fi ń gún ẹṣin, àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlá rẹ Ìwọ kò bo ọrun rẹ, o sì pè fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọfà ìwọ sì pín ayé níyà pẹ̀lú odò Àwọn òkè-ńlá ri ọ wọn ṣì wárìrì àgbàrá òjò ń ṣàn án kọjá lọ ibú ń ké ramúramù ó sì gbé irú omi sókè Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni ibùgbé wọn, pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ, àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà Ní ìrúnú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já, ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, fifi ìpìlẹ̀ hàn títí dé ọrùn pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde láti tú wá ká ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ talákà run ní kọ̀kọ̀ Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn òkun já, O tẹ òkun mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀, ìwọ fi àwọn ẹsin rẹ̀ rin òkun já, ó sì mu omi ńlá jáde okiki omi ńlá Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì, ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ, ẹ̀sẹ̀ mi sì wárìrì, mo dúró ni ìdákẹ́jẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná, tí èso kò sí nínú àjàrà tí iṣẹ igi olifi yóò jẹ́ àṣedànù, àwọn oko ki yóò sì mú oúnjẹ wá tí a ṣi ke agbo ẹran kúrò nínú agbo, tí ki yóò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùsọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀, èmi o layọ nínú Olúwa èmi yóò sí máa yọ nińú Ọlọ́run ìgbàla mi Olúwa Ọlọ́run ni agbára mi, òun yóò sí ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín, yóò sí mú mi rìn lórí ibi gíga Ṣi olórí akọrin lórí ohun èlò orin olókùn mi Ìpè Láti Tún Ilé Ní ọdún kejì ọba Dáríúsì ní ọjọ́ kìn-ín ní okìn-ín-ní oṣù kẹfà, ọ̀rọ̀ Olúwa wá nípasẹ̀ wòlíì Hágáì sí Serubábéli ọmọ Séítélì, Baálẹ̀ Júdà, àti Sọ́dọ̀ Jósúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí pé, Kò ti to àkókò láti kọ́ ilé Olúwa   Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hágáì wí pé Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fún ra yín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀sọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro Ní sinsinyìí, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ẹ kíyèsí ọ̀nà yín Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀ Ẹ̀yin jẹun, Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ Ẹ̀yin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò Báyìí ni Olúwa alágbára wí Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín Ẹ gun orí àwọn òkè ńlá lọ, kí ẹ sì mú igi wá pẹ̀lú yín Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí inú mi bà leè dùn sí i, kí a sì yín mí lógo, ni Olúwa wí Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsíi,, o yípadà sí díẹ̀ Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù Nítorí kí ni ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Nítorí ilé mi tí ó dáhoro tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀ Nítorí yín ni awọn ọ̀run ṣe dá ìrì dúró tí ilẹ̀ sì kọ̀ láti mu èso jáde Mo sì ti pe ọ̀dá sórí ilẹ̀ àti sórí awọn òkè-ńlá, sórí ọkà àti sórí wáìnì tuntun, sórí òróró àti sórí ohun ti ilẹ̀ ń mú jáde, sórí ènìyàn, sórí ẹran àti sórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín Nígbà náà ni Sérúbábélì ọmọ Séítíélì, Jósúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ìyókù, gba ohùn Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́ àti ọ̀rọ̀ wòlíì Hágáì, nítorí Olúwa Ọlọ́run ni ó rán an Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa Nígbà náà ni Hágáì ìránṣẹ́ Olúwa ń jíṣẹ́ Olúwa fún àwọn ènìyàn pé, Èmí wà pẹ̀lú yín, ni Olúwa wí Nítorí náà, Olúwa ru ẹ̀mí Sérúbábẹ́lì ọmọ Séítélì sókè, olórí Júdà àti ẹ̀mí Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà àti ẹ̀mí gbogbo ènìyàn ìyókù Wọ́n sì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lórí ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run wọn, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì ọba Dáríúsì Ìbìkún Fún Àwọn Ènìyàn Tí A Sọ Di Àìmọ́ Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje, ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá nípaṣẹ̀ wòlíì Hágáì wí pé Sọ fún Sérúbábélì ọmọ Séítélì, olórí Júdà, àti Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn yòókù Béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Ta ni nínú yín tí ó kù tí ó sì ti rí ilé yìí ní ògo rẹ̀ àkọ́kọ́ Báwo ni ó ṣe ri sí yín nísinsin yìí Ǹjẹ́ kò dàbí asán lójú yín Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, múra gírí, ìwọ Sérúbábélì, ni Olúwa wí Múra gírí, ìwọ Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà Ẹ sì múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà ni Olúwa wí, kí ẹ sì ṣiṣẹ́ Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Èyí ni ohun tí Èmi fi bá a yín dá májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Éjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí ì mi sì wà pẹ̀lú yín Ẹ má ṣe bẹ̀rù Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀ èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀ èdè yóò fà sí Tẹ́ḿpìlì yìí, Èmi yóò sì kùn ilé yìí pẹ̀lu ògo ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Tèmi ni fàdákà àti wúrà, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Ògo ìkẹyìn àwọn ọmọ-ogun ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn-án ní ọdún kejì Dáríúsì, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Hágáì wá pé Báyìí ni Olúwa alágbára wí Béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà ohun tí òfin wí pé Bí ẹnìkan bá gbé ẹran mímọ́ ní ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, tí ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ kan Búrẹ́dì tàbí ọbẹ̀, wáìnì, òróró tàbí oúnjẹ mìíràn, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ mímọ́ bí   Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́ Nígbà náà ni Hágáì wí pé, Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́ nipa fífi ara kan òkú bá fi ara kan ọkan lára nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ aláìmọ́ Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, Bẹ́ẹ̀ ni, yóò jẹ́ aláìmọ́ Nígbà náà ni Hágáì dáhùn ó sì wí pé,  Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn wọ̀nyí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi, ni Olúwa wí Bẹ́ẹ̀ sì ni olukuluku iṣẹ́ ọwọ́ wọn èyí tí wọ́n sì fi rúbọ níbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́  Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsí bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹ́ḿpìlì Olúwa Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìlé ogún, mẹ́wàá péré ni Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìfúntí wáìnì láti wọn àádọ́ta ìwọ̀n, ogún péré ni Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdú àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jà síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi, ni Olúwa wí Láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹ́sàn-án, yìí kí ẹ kíyèsí, kí ẹ sì rò ó dáradára, ọjọ́ ti a fi ìpìlẹ̀ tẹ́ḿpìlì Olúwa lé lẹ̀, ròó dáradára Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránátè, àti igi ólífì kò ì tíì so èso kankan  Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún-un yin   Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ Hágáì wá nígbà kejì, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà pé Sọ fún Sérúbábélì baálẹ̀ Júdà pé èmi yóò mi àwọn ọ̀run àti ayé Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́sin yóò ṣubú olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀ Olúwa àwọn wí pé, Ní ọjọ́ náà, àwọn ọmọ-ogun iwọ ìránṣẹ́ mi Sérúbábélì ọmọ Séítíélì, Èmi yóò mú ọ, Èmi yóò sì sọ ọ di bí òrùka èdìdì mi, nítorí mo ti yan ọ, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ọmọ Tí Ó Ṣe Pàtàkì Fún Àwọn Ańgẹ́lì Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà, ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jésù Kírísítì, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ Ọmọ tí í ṣe ìtànsán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkálárarẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ọlá-ńlá ní òkè Nítorí náà, ó sì ti fi bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ó ga ní ipò ju ańgẹ́lì lọ, bí ó ti jogún orúkọ èyí tí ó tayọ̀ ti wọn Nítorí kò sí ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì tí Ọlọ́run fi ìgbà kan sọ fún pé Ìwọ ni ọmọ mi lónì- ni mo bí ọ Àti pẹ̀lú pé Èmi yóò jẹ́ baba fún-un, Òun yóò sì jé ọmọ mi Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí Ó pàṣẹ pé, Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un Àti nípa ti àwọn ańgẹ́lì, ó wí pé Ẹni tí ó dá àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ ní ẹ̀mi, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ìná Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé, Ọlọ́run, ìjọba rẹ yóò wà láti ìran dé ìran, àti pé òdodo ni ọ̀pá tí ìwọ fi ń páṣẹ ìjọba rẹ Ìwọ fẹ́ òdodo, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi òróró ayọ̀ yàn ọ tí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ Ó tún sọ pé, Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀, àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀ gbogbo wọn ni yóò gbó di àkísà bí ẹ̀wù Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ, bí ìpàrọ̀ aṣọ ni a ó sì pàárọ̀ wọn Ṣùgbọ́n ìwọ fúnrarẹ kì yóò yípadà àti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin Èwo nínú àwọn ańgẹ́lì ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé, Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀ta rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ Kì í ha á ṣe ẹ̀mí tí ń jísẹ́ ni àwọn ańgẹ́lì í ṣe bí tí a rán lọ síta láti máa sisẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà Ìrúbọ Kírísítì Lẹ́ẹ̀kan Ṣoṣo Fún Gbogbo Ènìyàn Nítorí òfin, bí o ti ní òjìjì àwọn ohun rere ti ń bẹ̀ tí kì í ṣe àwòrán tóòtọ́ fún rere nǹkan náà, kò lè fi ẹbọ kan náà tí wọn ń rú nígbàgbogbo lọdọ́ọ̀dún mu àwọn tí ń wá sibẹ̀ di pípé Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, a kì ìbá tí dẹ́kun àti máa rú wọn, nítorí àwọn ti ń sìn ki ìbá tí ní ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a ba ti wẹ̀ wọ́n mọ́ lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo Ṣùgbọ́n nínú ẹbọ wọ̀nyí ni a ń ṣe ìranti ẹ̀ṣẹ̀ lọdọ́ọ̀dún Nítorí ko ṣeeṣe fún ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò Nítorí náà nígbà tí Kísítì wá sí ayé, ó wí pé, Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ, ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi Ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò ní inú dídùn sí Nígbà náà ni mo wí pé, Kíyèsí i mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run   Nígbà tí o wí ni ìṣáajú pé, Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọ̀rẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn Nígbà náà ni ó wí pé, Kíyèsí i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run O mu ti ìṣáaju kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀ Nípa ìfẹ́ náà ni a ti sọ wá di mímọ́ nípa ẹbọ ti Jésù Kírísítì fi ara rẹ̀ rú lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo Àti olukulùkù àlùfáà sì ń dúró lójoojúmọ́ láti ṣiṣẹ́ ìsìn, ó sì ń ṣe ẹbọ kan náà nígbàkúgbà, tí kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò láé Ṣùgbọ́n òun, lẹ̀yìn ìgbà tí o ti rú ẹbọ kan fún ẹ̀ṣẹ̀ títí láé, o jòkòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run Láti ìgbà náà, ó rétí títí a o fi àwọn ọ̀ta rẹ̀ ṣe àpótí itísẹ̀ rẹ̀ Nítorí nípa ẹbọ kan a ti mú àwọn tí a sọ di mímọ́ pé títí láé Ẹ̀mí mímọ́ sì ń jẹri fún wa pẹ̀lú Nítorí lẹ̀yìn tí ó wí pé, Èyí ni májẹ̀mú ti èmi o ba wọn dá lẹ́hìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí, èmi o fi òfin mi sí wọn ní ọkàn, inú wọn pẹ̀lú ni èmi o sì kọ wọn sí Ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédé wọn lèmi kì yóò sì rántí mọ́ Ṣùgbọ́n níbi tí ìmukúrò ìwọ̀nyí bá gbé wà, ìrubọ fún ẹ̀ṣẹ̀ kò sí mọ́ Ará, ǹjẹ́ bí a ti ní ìgboyà láti wọ inú ibi mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù, Nípa ọ̀nà títún àti ààyè, tí o yà sí mímọ́ fún wa, àti láti kọja aṣọ ìkelé èyí yìí ní, ara rẹ̀ Àti bí a ti ni àlùfáà gíga lórí ilé Ọlọ́run Ẹ jẹ́ kí a fi òtítọ́ ọkàn súnmọ́ tòòsí ni ẹ̀kún ìgbàgbọ́, kí a sì wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkan búburú, kí a sì fi omi mímọ́ wẹ ara wa nù Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìreti wa mu ṣinṣin ni àìsiyèméjì Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti ru ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere Kí a ma máa kọ ìpejọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni niyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ etílé Nítorí bí àwa ba mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́sẹ̀ lẹ̀yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ní lẹ̀rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀ta run Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Móṣè, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta Mélòómélòó ni ẹ rò pé a o jẹ Olúwa rẹ̀ ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹgan ẹmi oore òfẹ́ Nítorí àwa mọ ẹni tí o wí pé Ẹ̀san niti èmi, Olúwa wí pé, Èmi o gbẹ̀san Àti pẹ̀lú, Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ Ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè Ṣùgbọ́n ẹ rántí ọjọ́ ìṣáájú nínú èyí tí, nígbà tí a ti ṣi yin lójú, ẹ fi ara da wàhálà ńlá ti ìjìyà Lápakan, nígbà tí a ṣọ yín di ìran wíwò nípa ẹ̀gàn àti ìpọ́njú àti lápakan, nígbà tí ẹ̀yin di ẹ̀gbẹ àwọn tí a ṣe bẹ́ẹ si Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní suuru, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà Nítorí ni ìwọ̀n ìgbà díẹ̀ sí i, Ẹni náà ti ń bọ̀ yóò dé, kí yóò sì jáfara Ṣùgbọ́n olódodo ni yóò yè nípa ìgbàgbọ́ Ṣùgbọ́n bí o ba fà sẹ́yìn, ọkàn mi kò ní inú dídùn sí i Ṣùgbọ́n àwa kò sí nínú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sínú ègbé bí kò ṣe nínú àwọn tí o gbàgbọ́ sí ìgbàlà ọkàn Nípa Ìgbàgbọ́ Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ ní ìdánilójú ohun tí o ń réti, ìjeri ohun tí a kò rí Nítorí nínú rẹ ni àwọn alàgbà ní ẹ̀rí rere Nípa ìgbàgbọ́ ni a mọ̀ pé a ti dá ayé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nítorí náà kì í ṣe ohun tí o hàn ni a fi dá ohun tí a ń ri Nípa ìgbàgbọ́ ní Ábélì rú ẹbọ sí Ọlọ́run tí ó sàn ju ti Káínì lọ, nípa èyí tí a jẹ̀rí rẹ̀ pe olódodo ni, Ọlọ́run sí ń jẹ́ri ẹ̀bùn rẹ̀ Àti nípa rẹ̀ náà, bí o ti jẹ́ pé o ti kú, síbẹ̀ o ń fọhùn Nípa ìgbàgbọ́ni a sì Énókù nípò padà kí o má ṣe rí ikú a kò sí rí i, nítorí ti Ọlọ́run ṣi i nípò padà nítorí ṣaáju ìsìpo padà rẹ̀, a jẹ́ri yìí si i pé o wu Ọlọ́run Ṣùgbọ́n làísí ìgbàgbọ́ kò ṣeéṣe láti wù ú nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá kò lè sàì gbàgbọ́ pé o ń bẹ, àti pé òun ní olùṣẹ̀san fún àwọn tí o fi ara balẹ̀ wá a Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóàh, nígbà ti Ọlọ́run, kìlọ̀ ohun tí a kóò tíì rí fún un, o bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ilé rẹ̀, nípa èyí tí ó da ayé lẹ̀bí, ó sì di ajogún òdodo tí i ṣe nípa ìgbàgbọ́ Nípa ìgbàgbọ́ ní Ábúráhámù, nígbà tí a ti pé e láti jáde lọ sí ibi tí òun yóò gbà fún ilẹ̀ ìní, ó gbọ́, ó sì jáde lọ, láì mọ ibi tí òun ń rè Nípa ìgbàgbọ́ ní o ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí, bí ẹni pé ni ilẹ̀ àjèjì, o ń gbé inú àgọ́, pẹ̀lú Ísáákì àti Jákọ́bù, àwọn ajogún ìlérí kan náà pẹ̀lú rẹ̀ Nítorí tí ó ń rétí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀ ọ èyí tí Ọlọ́run tẹ̀dó tí o si kọ́ Nípa ìgbàgbọ́ ni Sárà tìkararẹ̀ pẹ̀lú fi gba agbára láti lóyún, nígbà tí ó kọja ìgbà rẹ̀, nítorí tí o ka ẹni tí o ṣe ìlérì sí olootọ́ Nítorí náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe ti ara ọkùnrin kan jáde, àní ara ẹni tí o dàbí òkú, ọmọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ́pọ̀lọpọ̀, àti bí ìyanrìn etí òkun láìníyè Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o kú ní ìgbàgbọ́, láì rí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, ti wọn si gbá wọn mú, tí wọn sì jẹ̀wọ́ pé àlejò àti àtìpó ni àwọn lórí ilẹ́ ayé Nítorí pé àwọn tí o ń ṣọ irú ohun bẹ́ẹ̀ fihàn gbangba pé, wọn ń ṣe àfẹ́rí ìlú kan tí i ṣe tiwọn Àti ní tòótọ́, ìbáṣe pé wọn fi ìlú ti wọn tí jáde wá sí ọkàn, wọn ìbá ti rí àyè padà Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n ń fẹ́ ìlú kan tí o dá jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí yìí ni ti ọ̀run nítorí náà ojú wọn kò ti Ọlọ́run, pé kí a máa pé òun ni Ọlọ́run wọn nítorí tí o ti pèsè ìlú kan sílẹ̀ fún wọn Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, nígbà tí a dan an wò, fi Ísáákì rúbọ àní òun ẹni tí ó rí ìlérí gba múra tan láti fi ọmọ bíbí rẹ kanṣoṣo rúbọ, Nípa ẹni tí wí pé, Nínú Ísáákì ni a o ti pé irú ọmọ rẹ̀ Ó sì rò ó si pé Ọlọ́run tilẹ̀ lè gbé e dìdè kúrò nínú òkú, bẹ́ẹ̀ ni, bí a bá sọ ọ lọ́nà àpẹẹrẹ, ó gbà á padà Nípa ìgbàgbọ́ ní Ísáákì súre fún Jákọ́bù àti Ísọ̀ níti ohun tí ń bọ̀ Nípa ìgbàgbọ́ ni Jákọ́bù, nígbà ti o ń ku lọ, ó súrre fún àwọn ọmọ Jósẹ́fù ni ìkọ̀ọ̀kan ó sì sìn ní ìtẹriba lé orí ọ̀pá rẹ̀ Nípa ìgbàgbọ́ ni Jósẹ́fù, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Ísraẹ́lì ó sì pàṣẹ níti àwọn egungun rẹ̀ Nípa ìgbàgbọ́ ní àwọn òbí Móṣè pa a mọ́ fún oṣù mẹ́ta nígbà tí a bí i, nítorí ti wọn rí i ní arẹwà ọmọ wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba Nípa ìgbàgbọ́ ni Móṣè, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọ-bìnrin Fáráò Ó kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgba díẹ̀ Ó ka ẹ̀gàn Kírísítì si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúrà Éjípítì lọ Nítorí tí ó ń wo èrè náà Nípa ìgbàgbọ́ ni o kọ Éjípítì sílẹ̀ láìbẹ̀rù ìbínú ọba nítorí tí o dúró ṣinṣin bí ẹni tí ó n ri ẹni àìrí Nípa ìgbàgbọ́ ni ó da àsè ìrekọjá sílẹ̀, àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀, kí ẹni tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ má báa fí ọwọ́ kan wọn Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la òkun púpa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀ Ti àwọn ara Éjípítì dánwo, ti wọn sì ri Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn odi Jẹ́ríkò wo lulẹ̀, lẹ̀yìn ìgbà tí a yí wọn ká ni ijọ́ méje Nípa ìgbàgbọ́ ni Ráhábù panṣágà kò ṣègbé pẹ̀lú àwọn tí kò gbọ́ràn nígbà tí o tẹ́wọ́gba àwọn àmì ní àlàáfíà Èwo ni èmi o sì tún máa wí sí i Nítorí pé ìgbà yóò kùnà fún mú láti sọ ti Gídíónì, àti Bárákì, àti Sámsónì, àti Jẹftà àti Dáfídì, àti Sámúẹ́lì, àti ti àwọn wòlíì Àwọn ẹni nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ti wọn sẹ́gun ilẹ̀ ọba, tí wọn ṣiṣẹ òdodo, ti wọn gba ìlérí, ti wọn dí àwọn kìnnìún lẹ̀nu, Tí wọn pa agbára iná, ti wọn bọ́ lọ́wọ́ ojú idà, tí a sọ di alágbára nínú àìlera, ti wọn dí akọni ni ìjà, wọn lé ogun àwọn àjèjì sá Àwọn obìnrin ri òkú wọn gbà nípa àjíǹde a sì da àwọn ẹlòmíràn lóró, wọ́n kọ̀ láti gba ìdásílẹ̀ kí wọn ba lè rí àjíǹde tí o dára jù gbà Àwọn ẹlòmíràn sì rí ìjìyà ẹ̀sín, àti nínà, àti ju bẹ́ẹ̀ lọ, ti ìdè àti ti túbú A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn wọn rìn kákiri nínú àwọ àgùntàn àti nínú àwọ ewúrẹ́ wọn di aláìní, olupọ́njú, ẹni tí a ń da lóró Àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún Wọn ń kiri nínú àsálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀ Gbogbo àwọn wọ̀nyí tí a jẹ́ri rere sí nípa ìgbàgbọ́, wọn kò sì rí ìlérí náà gbà Nítorí Ọlọ́run ti pèsè ohun tí o dárajù sílẹ̀ fún wa, pé láìsí wa, kí a má ṣe wọn pé Ìbáwí Àwọn Ọmọ Ọlọ́run Nítorí náà bí a ti fi ikúukùu àwọsánmà tí o kún fún àwọn ẹlẹ́ri tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tí si apákan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa, Kí a máa wo Jésù Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jóko lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run Má a ro ti ẹni tí ó faradà irú sọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́sẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má baa rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín Ẹ̀yin kò sáà tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yin sílẹ̀ nínú ìjakadi yín Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé, Ọmọ mi, ma ṣe aláìnánì ìbáwí Olúwa, kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí Nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i báwí, a sì máa na olukulùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gba Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í báwí Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, njẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn kò ha yẹ kí a kúkú tẹríbà fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o ba ti dára lójú wọn ṣùgbọ́n òun fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀ Gbogbo ìbáwí kò dábì ohun ayọ̀ nísinsìn yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́ ṣùgbọ́n níkẹ́yìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo Nítorí náà ẹ na ọwọ́ tí o rọ, àti èékún àìlera Kí ẹ sì ṣe ipa-ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin, kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kuku wò ó sàn Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kí Gbòngbò ìkoro kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́ Kí o má bá à si àgbérè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Èsau, ẹni tí o titorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀ Nítorí ẹ̀yin mọ pé lẹ̀yìn náà, nígbà tí ó fẹ láti jogún ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́, nítorí kò ri àyè ìronupìwàdà, bí o tilẹ̀ kẹ pé ó fi omijé wa a gidigidi Nítorí ẹ̀yin kò wá òkè tí a lè fi ọwọ́ kàn, àti ti iná ti ń jó, àti ti ìṣúdudu àti òkùnkùn, àti ìjì Àti ìró ìpè, àti ohùn ọ̀rọ̀, èyí tí àwọn tí o gbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé, kí a má ṣe sọ ọ̀rọ̀ si i fún wọn mọ́ Nítorí pé ara wọn kò lè gba ohun tí ó palaṣẹ, Bí o tilẹ̀ jẹ ẹranko ni o farakan òkè náà, a o sọ ọ ni òkúta, tàbí a o gun un ní ọ̀kọ̀ pa Ìran náà sì lẹ̀rù to bẹ́ẹ̀ tí Móṣè wí pé, Ẹrù ba mi gidigidi mo sì wárìrì Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Síónì, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerúsálémù ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn áńgẹ́lì àìníye, Si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé, o Àti sọ́dọ̀ Jésù alárinà májẹ̀mú titun, àti si ibi ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n ni, ti ń sọ̀rọ̀ ohun tí ó dára ju ti Ábélì lọ Kíyèsí i, kí ẹ má ṣe kọ̀ ẹni tí ń kìlọ̀ Nítorí bí àwọn wọ̀nyí kò bá bọ́ nígbà tí wọn kọ̀ ẹni ti ń kìlọ̀ ni ayé, mélomélo ni àwa kì yóò bọ́, bí àwa ba pẹ̀hìndè sí ẹni tí ń kìlọ̀ láti ọ̀run wá Ohùn ẹni ti o mi ayé nígbà náà ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti ṣe ìlérí, wí pé, Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi ki yóò mi kìkì ayé nìkan, ṣùgbọ́n ọ̀run pẹ̀lú Àti ọ̀rọ̀ yìí, Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìtumọ̀ rẹ̀ ni, mímú àwọn ohun wọ̀nyí ti a ń mì kúrò, bí ohun tí a ti dá, kí àwọn ohun tí a kò lè mì lè wà síbẹ̀ Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a ni oore-ọfẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́tẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀ Nítorí pé, Ọlọ́run wa, iná ti ń jó nírun ni Ìpari Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìyànjú Náà Kí ìfẹ́ ará o wà títí Ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣe àléjò nítorí pé nípa bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn ṣe àwọn áńgẹ́lì ní àlejò láìmọ̀ Ẹ máa rántí àwọn òǹdè bí ẹni tí a dè pẹ̀lú wọn, àti àwọn tí a ń pọn lójú bí ẹ̀yin tikarayin pẹ̀lú tí ń bẹ nínú ara Kí ìgbéyàwó lọ́lá láàrin gbogbo ènìyàn, kí àkéte si jẹ́ aláìléérí Nítorí àwọn àgbérè àti àwọn panṣágà ni Ọlọ́run yóò dá lẹ̀jọ́ Ki ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin nítorí oun tìkararẹ̀ ti wí pé, Èmi kò jẹ fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé, Olúwa ni oluranlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù kínni ènìyàn lè ṣe sí mi Ẹ máa rántí àwọn ti wọn jẹ́ aṣáájú yín, ti wọn ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín kí ẹ máa ro òpin ìwà-ayé wọn, kí ẹ sì máa ṣe àfarawé ìgbàgbọ́ wọn Jésù Kírísítì ọ̀kan náà ni lánà, àti lóní, àti títí láé Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè Àwa ní pẹpẹ kan, níbi èyí tí àwọn ti ń sin àgọ́ kò ni agbára láti máa jẹ Nítorí nígbà tí olórí àlùfáà bá mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran wá si ibi mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀, òkú àwọn ẹran náà ni a o sun lẹ̀yìn ibùdó Nítorí náà Jésù pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ̀yìn ìbodè Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ̀yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀ Nítorí pé àwa kò ní ìlú tí o wa títí níyin, ṣùgbọ́n àwa ń wá èyí tí ń bọ Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín funni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ Ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí ń ṣe olórí yín, kí ẹ sì máa tẹríbà fún wọ́n Nítorí wọn ń ṣọ́ ẹ̀sọ́ nítorí ọkàn yín, bí àwọn ti yóò ṣe ìsírò, kí wọn lè fi ayọ̀ ṣe èyí, kì í ṣe pẹ̀lú ìbànújẹ, nítorí èyí yìí yóò jẹ àìlérè fún yín Ẹ máa gbàdúrà fún wa Nítorí àwa gbàgbọ́ pé àwa ni ẹ̀rí ọkàn rere, a sì ń fẹ́ láti máa hùwà títọ́ nínú ohun gbogbo Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ̀ yín gidigidi sí i láti máa ṣe èyí, kí a ba lè tètè fi mi fún yín padà Ǹjẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà, ẹni tí o tún mu olùsọ́-àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn, ti inú òkú wá, nípa ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mu ayérayé, àní Olúwa wa Jésù Kí ó mú yín pé nínú iṣẹ́ rere gbogbo láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣiṣẹ ohun tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú rẹ̀ nínú yín nípasẹ̀ Jésù Kírísítì ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé Àmín Èmi sì ń bẹ̀ yín ará, ẹ gbà ọ̀rọ̀ ìyànjú mi nítorí ìwé kukuru ni mo kọ sí yín Ẹ mọ pé a sá Timótéù arákùnrin wa sílẹ̀ bí ó ba tètè dé, èmí pẹ̀lú rẹ̀ yóò rí yín, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ Ẹ ki gbogbo àwọn tí ń ṣe olórí yín, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ Àwọn tí o ti Ítalì wá ki yín Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo yín Àmín Ìkìlọ̀ Láti Ṣe Ìgbọràn Nítorí náà, ó yẹ kí àwa máa fi iyè sí àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì gidigidi tí àwa ti gbọ́, kí a má baà gbá wa lọ kúrò nínú wọn nígbà kan Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tí ẹnu àwọn ańgẹ́lì sọ bá sì dúró ṣinṣin, àti tí olúkúlùkù ẹ̀sẹ̀ sí òfin àti àìgbọ́ràn gba ìjìyà tí ó tọ́ sí i, kí ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí Ìgbàlà tí Olúwa fúnraarẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀ Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ àmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀ Nítórí pé, kì í ṣe abẹ́ ìsàkóso àwọn ańgẹ́lì ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ańgẹ́lì lọ ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé, ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ Ní ti fí fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀ Ṣíbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ Ṣùgbọ́n àwa rí Jésù ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ańgẹ́lì lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jésù, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe Balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà Nítorí àti ẹni tí ń sọni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá Nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin Wí pé, Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi, ni àárin ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀ Àti pẹ̀lú, Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi lé e Àti pẹ̀lú, Kíyèsi í, èmi rèé, èmi àti àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi fún mi Ǹjẹ́ ni ìwọ̀n bí àwọn ọmọ tí ṣe alábàápín ará àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òun pẹ̀lú sì ṣe alábàápín nínú ohun kan náà kí ó lè ti ipa ikú rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára ikú run, èyí ni Èṣù Kí o sì lè gba gbogbo àwọn tí ó tìtorí ìbẹ̀rù ikú wà lábẹ́ ìdè lọjọ ayé wọn gbogbo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù Nítorí pé, nítòótọ́, kì í ṣe àwọn ańgẹ́lì ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ṣùgbọ́n àwọn irú-ọmọ Ábúráhámù ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòótọ́ Olórí Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn Nítorí níwọ̀n bí òun tìkararẹ̀ ti jìyà tí a sì ti dán an wò, òun ní agbára láti ran àwọn tí a ń dánwò lọ́wọ́ Jésù Pọ̀ Ju Mósè Lọ Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábàápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti Àpósítélì àti Olórí Àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jésù Ẹni tí o ṣe olóòótọ́ si ẹni tí ó yàn án, bí Mósè pẹ̀lú tí ṣe olóòótọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo ilé Ọlọ́run Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mósè lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run Mósè nítòótọ́ sì ṣe olóòótọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ̀n ní ìgbà ìkẹyìn Ṣùgbọ́n Kírísítì jẹ́ olóòtọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run ilé ẹni tí àwá jẹ́, bí àwá bá gbẹ́kẹ̀ lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mi Mímọ́ tí wí Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀, Ẹ má ṣe sé ọ̀kan yin le, bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀, bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní ihà Níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò, tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà, mo sì wí pé, Nígbà gbogbo ni wọn sìnà ní ọkàn wọn wọn kò sì mọ ọ̀nà mi Bí mo tí búra ní ìbínú mi, wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi   Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjù ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní Òní, kí a má ba à sé ọkàn ẹnìkẹni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀ Nítorí àwá di alábàápín pẹ̀lú Kírísítì, bí àwá bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin Nígbà tí a ń wí pé Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má se ọ̀kan yin le, bí ìgbà ìmúnibínú Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Éjíbítì ní abẹ́ àkóso Mósè Àwọn ta ni ó sì bínú sí fún ogójì ọdún Kì í ha ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀, òkú àwọn tí ó sùn ní ihà Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn Àwá sì rí i pé wọn kò lè wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbàgbọ́ Ìsinmi Fún Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí àti wọ inú ìsinmi rẹ̀ fún wa, ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù, kí ẹnikẹ́ni nínú yín má baà dà bí ẹni pé ó tí kùnà rẹ̀ Nítorí tí àwá gbọ́ ìwàásù ìyìn rere, gẹ́gẹ́ bí a ti wàásù rẹ̀ fún àwọn náà pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ kò ṣe wọ́n ní ire, nítorí tí kò dàpọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú àwọn tí ó gbọ́ ọ Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí, Bí mo tí búra nínú ìbínú mi, Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi   Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpilẹ̀ ayé Nítorí ó ti sọ níbìkan ní ti ọjọ́ kéje bayìí pé, Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo Àti níhìn yìí pẹ̀lú ó wí pé, Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi Nítorí náà bí ó tí jẹ́ pé, ó ku kí àwọn kan wọ inú rẹ̀, àti àwọn tí a tí wàásù ìyìn rere náà fún ní ìṣáajú kò wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbọ́ràn Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dáfídì pé, Lònìí, lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀ bí a tí wí niṣáájú, Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe sé ọkàn yín le Nítorí, ìbá ṣe pé Jóṣúà tí fún wọn ní ìsinmi, òun kì bá tí sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìsinmi mìíràn lẹ̀yìn náà, nítorí náà ìsinmi kan kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run Nítorí pé ẹni tí ó ba bọ́ sínú ìsinmi rẹ̀, òun pẹ̀lú sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀ Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á múra gírí láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má baà ṣubú nípa irú àìgbàgbọ́ kan náà Nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ní agbára, ó sì mu ju idàkídà olójú-méjì lọ, ó sì ń gunni àní títí dé pínpín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti ní oríkèé àti ọ̀rá inú egungun, òun sì ni olùmọ̀ èrò inú àti ète ọkàn Kò sí ẹ̀dá kan tí kò farahàn níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni ó wà níhòòhò tí a sì ṣípayá fún ojú rẹ̀, níwájú ẹni tí àwa yóò jíyìn Ǹjẹ́ bí a ti ní olórí àlùfáà ńlá kan, tí ó ti la àwọn ọ̀run kọjá lọ, Jésù ọmọ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ wa mú ṣinṣin Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì báni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́sẹ̀ Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a wá si ibi ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí oore-ọ̀fẹ́ láti máa ranni lọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀ Ìkìlọ̀ Lórí Síṣubú Kúrò Nínú Ìgbàgbọ́ Nítorí olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan tí a yàn nínú àwọn ènìyàn, ní a fi jẹ nítorí iṣẹ́ ìsìn àwọn ènìyàn sí Ọlọ́run láti máa mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ẹni tí ó lè bá àwọn aláìmòye àti àwọn tí ó ti yapa kẹ̀dùn, nítorí a fi àìlera yí òun náà ká pẹ̀lú Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe yẹ, bí ó ti ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ń se fún ara rẹ̀ náà Ko sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò se ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Árọ́nì Bẹ́ẹ̀ ni Kírísítì pẹ̀lú kò si ṣe ara rẹ̀ lógo láti jẹ́ olórí àlùfáà bí kò ṣe ẹni tí o wí fún ún pé, Ìwọ ni ọmọ mi, lónìn-ín ni mo bi ọ Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibò mìíràn pé, Ìwọ ni àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melikisédékì Ní ìgbà ọjọ́ Jésù nínú ayé, ó fi ẹkún rara àti omije gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀ Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ gbọ́ràn nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀ Bí a sì ti sọ ọ di pípé, o wa di orísun ìgbàlà àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó ń gbọ tirẹ̀ Tí a yàn ní Olórí àlùfáà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ní ipasẹ̀ Melikisédékì Nípa èyí àwá ní ohun púpọ̀ láti sọ, tí ó sì ṣòro láti túmọ̀, nítorí pé ẹ yigbì ní gbígbọ́ Nítorí pé báyìí ó ti yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ní, ẹ tún wà ní ẹni tí ẹnìkan yóò máa kọ́ ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ sì tún di irú àwọn tí ó mu wàrà, tí wọn kò sì fẹ́ oúnjẹ líle Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń mu wàrà jẹ́ aláìlóye ọ̀rọ̀ òdodo nítorí ọmọ ọwọ́ ni Ṣùgbọ́n oúnjẹ líle wà fún àwọn tí ó dàgbà, àwọn ẹni nípa ìrírí, tí wọn ń lo ọgbọ́n wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàrin rere àti búburú Ìdánilójú Ìlérí Ọlọ́run Nítorí náà, ó yẹ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà tí a sẹ̀sẹ̀ gba Kírísítì sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò mú wa dàgbà sókè ní pípé Láìtún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ bí i ìrònúpìwàdà kúrò nínú òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ síhà ti Ọlọ́run, ti ẹ̀kọ́ àwọn bamitísìmù, àti ti ìgbọ́wọ́-léni, ti àjíǹde òkú, àti tí ìdájọ́ àìnípẹ̀kun Èyí ní àwá yóò sì ṣe bí Ọlọ́run bá fẹ́ Nítorí pé, kò ṣe é ṣe fún àwọn tí a ti là lójú lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n sì ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, tí wọn sì ti di alábàápín Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọn sì tọ́ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run wò, àti agbára ayé tí ń bọ̀, láti tún sọ wọ́n di ọ̀tun sí ìrònúpìwàdà bí wọn bá ṣubú kúrò nítorí tí wọ́n tún kan ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélèbú sí ara wọn lọ́tún, wọ́n sì dójú tì í ní gbangba Nítorí ilẹ̀ tí ó ń fa omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ nígbà gbogbo mu, tí ó sì ń hú ewébẹ̀ tí ó dára fún àwọn tí à ń tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń gba ìbùkún lọ́wọ́ Ọlọ́run Ṣùgbọ́n bí ó ba ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò di kíkọ̀sílẹ̀, kò si jìnnà sí fífi gégùn ún, òpin èyí tí yóò wà fún ìjóná Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwá ní ìgbàgbọ́ ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní ti yín, àti ohun tí ó faramọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀ Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yín fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe Àwá sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsinmi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí Nítorí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Ábúráhámù, bí kò ti rí ẹni tí ó pọ̀jù òun láti fi búra, ó fi ara rẹ̀ búra, wí pé, Nítòótọ́ ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ̀yìn ìgbà tí Ábúráhámù fi súúrù dúró, ó ri ìlérí náà gbà Nítorí ènìyàn a máa fi ẹni tí ó pọ̀jù wọ́n lọ búra ìbúra náà a sì fi òpin sí gbogbo ìjiyàn wọn fún ìfẹ̀ṣẹ̀ múlẹ̀ ọ̀rọ̀ Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidgidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrin wọn Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú sinsin Èyí tí àwa ní bi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ̀yìn aṣọ ìkélé Níbi tí Jésù, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ Olórí àlùfáà títí láé nípasẹ̀ Melekisédékì Melikisédékì Jẹ́ Àlùfáà Nítorí Melikisédékì yìí, ọba Sálẹ́mù, àlùfáà Ọlọ́run ọ̀gá ògo, ẹni tí ó pàdé Ábúráhámù bí ó ti ń padà bọ̀ láti ibi pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un Ẹni tí Ábúráhámù sì pin ìdámẹ́wàá ohun gbogbo fún lọ́nà èkíniní nínú ìtumọ̀ rẹ̀, Ọba òdodo, àti lẹ̀yìn náà pẹ̀lú, ọba Sálẹ́mù, tí í ṣe ọba àlàáfíà Láínì baba, láìní ìyá, láìní ìtàn ìran, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọjọ́ ayé ṣùgbọ́n a ṣe é bí ọmọ Ọlọ́run ó wà ní àlùfáà títí Ǹjẹ́ ẹ gbà á rò bí ọkùnrin yìí ti pọ̀ tó, ẹni tí Ábúráhámù baba ńlá fi ìdámẹ́wàá nínú àwọn àṣàyàn ìkógun fún Àti nítòótọ́ àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Léfì, tí o gba oyè àlùfáà, wọ́n ní àṣẹ láti máa gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí òfin, èyí yìí, lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí ó tilẹ̀ ti jẹ́ pé, wọn ti inú Ábúráhámù jáde Ṣùgbọ́n òun ẹni tí a kò tilẹ̀ pìtàn ìran rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn wá, gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ Ábúráhámù, ó sì súre fún ẹni tí ó gba ìlérí, láìsí ìjìyàn rárá ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láàyè ni Àti níyin, àwọn ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láàyè nì Àti bí a ti lè wí, Léfì pàápàá tí ń gba ìdámẹ́wàá, ti san ìdámẹ́wàá nípasẹ̀ Ábúráhámù Nítorí o sáa sì ń bẹ ní inú baba rẹ̀, nígbà ti Melikísédékì pàdé rẹ̀ Ǹjẹ́ ìbá ṣe pé pípé ń bẹ nípa oyè àlùfáà Léfì, , kínni ó sì tún kù mọ́ tí àlùfáà mìíràn ìbá fi dìde ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Melikísédékì, tí a kò si wí pé ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Árọ́nì Nítorí pé bí a ti ń pààrọ̀ iṣẹ́ àlùfáà, a kò sì lè ṣàì máa pààrọ̀ òfin Nítorí ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, láti inú èyí tí ẹnikẹ́ni kòì jọ́sìn rí níbi pẹpẹ Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Júdà ni Olúwa wa ti dìde nípa ẹ̀yà yìí Mósè kò sọ ohunkóhun ní ti àwọn àlùfáà Ó sì tún hàn gbangba ju bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ pé àlùfáà míràn dìde ní àpẹẹrẹ ti Melikísédékì Èyí tí a fi jẹ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin nípa ti ara, bí kò ṣe nípa agbára ti ìyè àìlópin Nítorí a jẹri pé Ìwọ ni àlùfáà títí láé ní ipaṣẹ̀ ti Melikísédékì Nítorí a mú òfin ìṣáájú kúrò nítorí àìléera àti àìlérè rẹ̀ , a sì mú ìrètí tí ó dára jù wá nípa èyí tí àwa ń súnmọ́ Ọlọ́run Níwọ̀n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni Nítorí àwọn àlùfáà tẹ́lẹ̀ jẹ oyè láìsí ìbúra, ṣùgbọ́n ti òún jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nípa ẹni tí ó wí fún un pé, Olúwa búra, kí yóò sì yí padà Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé ni ipasẹ̀ ti Mekisédékì   Níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni Jésù ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù Àti nítòótọ́ àwọn púpọ̀ ní a ti fi jẹ àlùfáà, nítorí wọn kò lè wà títí nítorí ikú Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ nípò Nítorí náà ó sì le gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nipasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí o ń bẹ láàyè títí láé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn Nítorí pé irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀ ni o yẹ wá, mímọ́, àìlẹ́gàn, àìléèérí, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbéga ju àwọn ọ̀run lọ Ẹni tí kò ní láti máa rúbọ lójojúmọ́, bí àwọn olórí àlùfáà, fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀ náà, àti lẹ̀yìn náà fún tí àwọn ènìyàn nítorí èyí ni tí ó ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ Nítorí pé òfin a máa fi àwọn ènìyàn tí ó ní àìlera jẹ olórí àlùfáà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ti ìbúra, tí ó ṣe lẹ̀yín òfin, ó fi ọmọ jẹ ẹni tí a sọ di pípé títí láé Olórí Àlùfáà Ti Májẹ̀mú Tuntun Nísinsin yìí, kókó ohun tí à ń sọ nìyí Àwá ní irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀, tí ó jokòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ ọla ńlá nínú àwọn ọ̀run Ìránṣẹ́ ibi mímọ́, àti ti àgọ́ tóòtọ́, tí Olúwa pa, kì í ṣe ènìyàn Nítorí a fi olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan jẹ láti máa mú ẹ̀bùn wá láti máa rúbọ Nítorí náà ó ṣe pàtàkì fún eléyìí náà láti ní nǹkan tí ó máa fi sílẹ̀ Tí ó bá jẹ́ pé ó wà ní ayé ni, òun kì bá ti jẹ́ àlùfáà, nítorí pé àwọn ọkùnrin tí ó ń fi ẹ̀bùn sílẹ̀ ti wà bí òfin ṣe là á sílẹ̀ Àwọn ẹni tí ń sìn nínú pẹpẹ kan tí ó jẹ́ ẹ̀dá àti òjìji ohun tí ń lọ́run Ìdí abájọ nìyí tí a fi kìlọ̀ fún Mósè nígbà tí ó kọ́ àgọ́ Nítorí ó wí pé, Kíyèsí kí o ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fihàn ọ lórí òkè Ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ni ọlá jù, níwọ̀n bí o ti jẹ pé alárinà májẹ̀mú tí o dára jù ní i ṣe, èyí tí a fi ṣe òfin lórí ìlérí tí o sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣaajú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá àyè fún èkejì Nítorí tí o rí àbùkù lára wọn, ó wí pé, Kíyèsí i ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, ti èmi o bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mu títún Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú tí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jáde kúrò ní Íjíbítì, nítorí wọn kò jẹ́ olótítọ́ sí májẹ̀mú mi èmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wí ni Olúwa wí Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ̀yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn, èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn, èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀, tàbi olukulùkù arákùnrin rẹ̀, pé, mọ Olúwa, Nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí, láti kékere dé àgbà Nítorí pé èmi ó ṣáànu fún àìṣódodo wọn, àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àiṣedeede wọn lèmí ki yóò sì rántí mọ́ Ní èyí tí ó wí pé, Májẹ̀mu títún ó ti sọ ti ìṣáájú di ti láéláé Ṣùgbọ́n èyí tí ó ń di i ti láéláé tí ó sì ń gbó, o múra àti di asán Ìsìn Nínú Àgọ́ Ayé Yìí Bẹ́ẹ̀ ni májẹ̀mú àkọ́kọ́ ní ìlànà fún ìsìn àti ibi mímọ́ ti ayé yìí A gbé agọ́ kan dìde Nínú yàrá rẹ̀ àkọ́kọ́ ni a ti rí ọ̀pá fìtílà, tábìlì, àti àkàrà ìfihàn Èyí tí a ń pè ní ibi mímọ́ Àti lẹ́yìn aṣọ ìkelé kejì, òun ni àgọ́ tí à ń pè ní ibi mímọ́ jùlọ Tí ó ní àwo tùràrí wúrà, àti àpótí májẹ̀mú tí a fi wúrà bò yíká, nínú èyí tí ìkòkò wúrà tí ó ní mánà gbé wà, àti ọ̀pá Árónì tí o rúdí, àti àwọn wàláà májẹ̀mú Àti lórí rẹ̀ ni àwọn kérúbù ògo ti i ṣíji bo ìtẹ́ àánú èyí tí a kò lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ nísinsin yìí lọ́kọ̀ọ̀kan Ǹjẹ́ nígbà tí a ti ṣe ètò nǹkan wọ̀nyí báyìí, àwọn àlùfáà a máa lọ nígbàkúgbà sínú àgọ́ èkínní, wọn a máa ṣe iṣẹ́ ìsìn Ṣùgbọ́n sínú èkejì ni olórí àlùfáà nìkan máa ń lọ lẹ́kan ṣoṣo lọ́dún, fún ara rẹ̀, àti fún ìsìnà àwọn ènìyàn Ẹ̀mí mímọ́ ń tọ́ka èyí pé a kò ì tí ì ṣí ọ̀nà ibi mímọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ èkíní bá sì dúró, Gẹ́gẹ́ bí ètò yìí, a ń mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá, tí kò lè mú ẹ̀rí ọkàn olùsìn di pípé, Èyí sì wà nínú ohun jíjẹ àti ohun mímu àti onírúurú ìwẹ̀, tí ì iṣe ìlànà ti ara nìkan tí a fi lélẹ̀ títí fi di ìgbà àtúnṣe Ṣùgbọ́n nígbà tí Kírísítì dé bí Olórí àlùfáà àwọn ohun rere tí ń bọ̀, nípaṣẹ̀ àgọ́ tí o tóbi ti ó sì pé ju ti ìṣáájú, , Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ọmọ màlúù, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkararẹ̀, o wọ ibi mímọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáǹdè àìnípẹ̀kun gbà fún wa Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti akọ màlúù àti eerú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí a ti sọ di aláìmọ́ ba ń sọni-di-mímọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ ara Mélòómélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kírísítì, ẹni, nípa Ẹ̀mí ayérayé, tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbàwọ́n, yóò wẹ èérí ọkàn yín nù kúrò nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alààyè Àti nítorí èyí ni ó ṣe jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun pé bí ikú ti ń bẹ fún ìdáǹdè àwọn ìrékọjá ti o tí wà lábẹ́ májẹ̀mú ìṣáájú, kí àwọn tí a ti pè lè rí ilèrí ogún àìnípẹ̀kun gbà Nítorí níbi tí ìwé ogún bá gbé wà, ikú ẹni tí o ṣe é kò lè ṣe àìsí pẹ̀lú Nítorí ìwé ogún ní agbára lẹ̀yìn ìgbà tí ènìyàn bá kú Nítorí kò ní agbára rárá nígbà tí ẹni tí o ṣè e bá ń bẹ láàyè Nítorí náà ni a kò ṣe ya májẹ̀mú ìṣáájú páàpáà sí mímọ́ láìsí ẹ̀jẹ̀ Nítorí nígbà tí Mósè ti sọ gbogbo àṣẹ nípa ti òfin fún gbogbo àwọn ènìyàn, ó mú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù àti ti ewúrẹ́, pẹ̀lú omi, àti òwú òdòdó, àti ewé hísọ́pù ó sì fi wọ́n àti ìwé páàpáà àti gbogbo ènìyàn Wí pé, Èyí ní ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run paláṣẹ fún yín Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n àgọ́, àti gbogbo ohun èlò ìsìn Ó sì fẹ́rẹ̀ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀nù gẹ́gẹ́ bí òfin àti pé láìsí ìtàjẹ̀sílẹ̀ kò sí ìdáríjì Nítorí náà a kò lè ṣàì fi ìwọ̀nyí we àwọn àpẹẹrẹ ohun tí ń bẹ lọ́run mọ́ ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run páàpáà mọ́ ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ji ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run páàpáà mọ́ Nítorí Kírísítì kò wọ ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe lọ tí i ṣe àpẹẹrẹ ti òtítọ́ ṣùgbọ́n ó lọ sí ọ̀run páàpáà, nísinsin yìí láti farahàn ní iwájú Ọlọ́run fún wa Kì í si i ṣe pé kí ó lè máa fi ara rẹ̀ rúbọ nígbàkúgbà, bí olórí àlùfáà tí máa ń wọ inú ibi mímọ́ lọ lọ́dọọdún ti oun pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ti kì í ṣe tirẹ̀ Bí bẹ́ẹ̀ bá ni oun ìbá tí máa jìyà nígbàkúgbà láti ìpìlẹ̀ ayé Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ni ó fi ara hàn lẹ́ẹ́kanṣoṣo lópìn ayé láti mi ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípa ẹbọ ara rẹ̀ Níwọ̀n bí a sì ti fi lélẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti kú lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo, ṣùgbọ́n lẹ̀yìn èyí ìdájọ́ Bẹ́ẹ̀ ni Kírísítì pẹ̀lú lẹ̀yìn tí a ti fi rúbọ lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, yóò farahàn ní ìgbà kéjì láìsí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí n wo ọ̀nà rẹ̀ fún ìgbàlà Ìdílé Hósíà Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Hósíà ọmọ Béérì wá ní àkókò ìjọba Ùsáyà, Jótamù, Áhásì àti Heṣekáyà àwọn ọba Júdà àti ní àkókò ọba Jéróbóámù ọmọ Jóásì ní Ísírẹ́lì Nígbà tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hósíà, Olúwa wí fún un pé, Lọ, fẹ́ àgbèrè obìnrin kan fún araa rẹ, kí ó sì bí ọmọ àgbèrè fún ọ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn, nítorí ilẹ̀ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè púpọ̀ nípa yíyapa kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Nígbà náà ni ó sì lọ, ó sì fẹ́ Gómérì ọmọbìnrin Díbíláémù, ọmọbìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Hósíà pé, Pe orúkọ ọmọ náà ní Jésírẹ́lì, nítorí pé láìpẹ́ ni èmi yóò jẹ ìdílé Jéhù ní ìyà fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn tó pa ní ìpakúpa ní Jésírẹ́lì, Èmi yóò sì mú ìjọba Ísírẹ́lì wá sí òpin Ní ọjọ́ náà ni Èmi yóò sẹ́ ọrun Ísírẹ́lì ní àfonífojì Jésírẹ́lì Gómérì sì tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan Olúwa sọ fún un pé, Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-rúhámà, nítorí pé Èmi kò ní ṣàánú fún ilé Ísírẹ́lì mọ́, Èmi kò sì ní dáríjì wọ́n Síbẹ̀, èmi yóò ṣàáànú fún ilé Júdà, èmi ó gbà wọ́n—kì í ṣe nípa ọfà, idà tàbí ogun, ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin bí kò ṣe nípa Olúwa Ọlọ́run wọn Lẹ́yìn ìgbà tí ó Lo-rúhámà, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn Nígbà náà ni Olúwa sì sọ fún un pé, Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-ámì, nítorí pé ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọ́run yín Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò pọ̀ bíi iyanrìn etí òkun tí a kò le wọ̀n, tí a kò sì le è kà, yóò síṣe Ní ibi tí wọ́n ti sọ fún wọn pé Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi, níbẹ̀ ni a ó ti máa pè wọ́n ní ọmọ Ọlọ́run alààyè Àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì yóò para pọ̀, wọn yóò sì yan olórí kan tí yóò jáde láti ilẹ̀ náà, nítorí pé ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jésírẹ́lì yóò jẹ́ Ísírẹ́lì jẹ́ igi àjàrà tó gbalé ó ń sọ èṣo fún ara rẹ̀ Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere Ó bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀ Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀ yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, A kò ní ọba nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwa ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba, kí ni yóò se fún wa Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀, wọ́n ṣe ìbúra èké, wọ́n da májẹ̀mú báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko, bi i koríko májèlé láàrin oko tí a ro Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samáríà bẹ̀rù nítorí ere màlúù tó wà ní Bẹti-Áfẹ́nì Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀ Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀, nítorí ogo rẹ̀ nítorí o tí lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ A ó gbé lọ sí Ásíríà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá a ó dójú ti Éfúráímù oju yóò ti Ísírẹ́lì nítorí ere òrìṣà rẹ̀ Bí igi tó léfòó lórí omi ni Samaríà àti àwọn ọba rẹ yóò ṣàn lọ Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà buburú ni a o parun— Ẹ̀sẹ̀ Ísírẹ́lì ni Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde, yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, Bò wá mọ́lẹ̀! àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, Ṣubú lù wá! Láti ìgbà Gíbíà, ni ó ti sẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì ìwọ sì tún wà níbẹ̀ Njẹ́ ogun kò lé ẹ̀yin aṣebi ni Gíbíà bá bí Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n Orílẹ̀ èdè yóò kó ra wọn jọ wọ́n ó sì dojú kọ wọn Láti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn Éfúráímù jẹ́ ọmọ màlúù tí a tí kọ́, to si fẹ́ràn láti máa pa ọkà lórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà ni èmi ó dí ẹru wúwo lé Èmi yóò mú kí a gun Éfúráímù bí ẹṣin Júdà yóò tú ilẹ̀, Jákọ́bù yóò sì fọ́ ogúlùtu rẹ̀ Ẹ gbin òdòdó fún ara yín kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin, Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kòro nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa , títí tí yóò fi dé, tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí Ṣùgbọ́n ẹ tí gbìn buburú ẹ si ka ibi, Ẹ ti jẹ èso èké nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀ lé agbára yín àti àwọn ọ̀pọ̀ jagun jagun yín ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yín kí gbogbo odi agbára yín ba le parun Gẹ́gẹ́ bí Ṣalìmanì ṣe pa Bétí-Ábélì run lọ́jọ́ ogun, nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn Báyìí ni a o sì ṣe sí ọ, ìwọ Bétélì, nítorí pé ìwà buburú yín ti pọ̀jù Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà, a o pa ọba Ísírẹ́lì run pátapáta Ìfẹ́ Ọlọ́run Sí Ísírẹ́lì Nígbà tí Ísírẹ́lì wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀, mo sì pe ọmọ mi jáde wá láti Éjíbítì Wọ́n rúbọ sí Báálì bí mo ṣe ń pe Ísírẹ́lì sí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi jìnnà sí i wọn rúbọ sí báálímu, wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín Lóòtọ́ mo kọ́ Éfúráímù pẹ̀lú ní ìrìn mo di wọ́n mú ní apá, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo ti mú wọn lára dá Mo fó okùn ènìyàn fà wọ́n àti ìdè ìfẹ́ Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn Mo sì farabalẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ Ṣé wọn ò wá ní padà sí Éjíbítì bí Ṣé Ásíríà kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronú pìwàdà Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn yóò si bá gbogbo irin ẹnú odi ìlú wọn jẹ́ yóò sì fòpin sí gbogbo èrò wọn Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi Bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ ọ̀gá-ògo júlọ, kò ní gbé wọn ga rárá Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Éfúráímù Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Ísírẹ́lì Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ádímà Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ṣébóímù Ọkàn mi yípadà nínú mi Àánú mi sì ru sókè Èmi kò ni i mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ tàbí kí èmi wá sọ Éfúráímù di ahoro Nítorí pé Ọlọ́run ni àni, èmi kì í ṣe ènìyàn Ẹni mímọ́ láàrin yín, Èmi kò ni i wa nínú ìbínú Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún Nígbà tó bá bú àwọn ọmọ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀ oòrùn Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù bi i ẹyẹ láti Éjíbítì bi i àdàbà láti Ásíríà Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn, ni Olúwa wí Éfúráímù tí fi irọ́ yí mi ká ilé Ísírẹ́lì pẹ̀lú ẹ̀tàn Ṣùgbọ́n Júdà sì dúró ṣinṣin pẹ̀lú Ọlọ́run Ó sì ṣe olóòótọ́ sí Ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì Éfúráímù ń jẹ afẹ́fẹ́ Ó n lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀ oòrùn ní gbogbo ọjọ́ Ó sì ń gbèrú nínú irọ́ Ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ásíríà Ó si fi òróró ólífì ránsẹ́ sí Éjíbítì Olúwa ní ẹ̀sùn tí yóò fí kan Júdà yóò fìyà jẹ Jákọ́bù gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ yóò sì sán fún-un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀ Láti inú oyun ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀, àti nípa ìpá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run Ó bá ángẹ́lì ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀ Ó sunkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere rẹ̀ Ó bá Olúwa ní Bẹ́tẹ́lì Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀, àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀ Ṣùgbọ́n ìwọ́ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀ Di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú kí ẹ sì dúró de Olúwa yín nígbà gbogbo Oníṣòwò ń lo òṣùnwọ̀n èké Ó fẹ́ràn láti rẹ́nijẹ Éfúráímù gbéraga, Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́ Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́ bí i ọjọ́ àjọ mímọ́ wọ̀n ọn nì Mo sọ fún àwọn wòlíì, mo fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran hàn wọ́n mo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn Gílíádì ha burú bí Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rúbọ ní Gílígálì Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebè nínú aporo oko Jákọ́bù sá lọ si orílẹ̀ èdè Árámù Ísírẹ́lì sìn kí o tó fẹ ìyàwó ó ṣe ìtọjú ẹran láti fi san owó ìyàwó Olúwa lo wòlíì kan láti mú Ísírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì, nípaṣẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀ Ṣùgbọ́n Éfúráímù ti mú un bínú gidigidi Olúwa rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ sí orí rẹ̀ òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀ Ìbínú Nígbà Éfúráímù bá ń ṣọ̀rọ̀, àwọn ènìyàn máa ń wárìrì, a gbé e ga ní Ísírẹ́lì ṣùgbọ́n ó jẹ̀bi ẹ̀ṣùn pé ó ń sin òrìṣà Báálì, ó sì kú Báyìí, wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ wọn fi fàdákà ṣe ère òrìṣà fúnra wọn ère tí a fi ọgbọ́n dá àrà sí gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà Wọn ń sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí Pé, Jẹ́ kí àwọn Ènìyàn tí ń rúbọ fi ẹnu ko àwọn màluu ni ẹnu Nítorí náà wọn yóò dàbí ìkùùkù òwúrọ̀, bí ìrì òwúrọ̀ kùtùkùtù tó máa ń parẹ́, bí i èèpo ọkà tí afẹ́fẹ́ gbé láti ibi ìpakà bí èéfín tó rú jáde gba ojú fèrèsé Ṣùgbọ́n Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ẹni tó mú ọ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá Ìwọ̀ kì yóò sì mọ ọlọ́run mìíràn àfi èmi kò sí olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn èmi Mo ṣe ìtọ́jú rẹ ní ihà ní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí kò ní omi Wọn ni ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí mo fún wọn ní oúnjẹ Nígbà tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tan wọ́n di agbéraga Nígbà náà ni wọ́n sì gbàgbé mi Nítorí náà, Èmi yóò dìde sí wọn bí i kìnnìún Èmi yóò farapamọ́ dè wọ́n lọ́nà bí i ẹkùn Béárì igbó tí a já ọmọ rẹ̀ gbà Èmi yóò bá wọn jà bí Èmi yóò sì fà wọ́n ya bí ìgbà tí ẹkùn bá fa ara wọn ya A ti pa ọ́ run, ìwọ Ísírẹ́lì nítorí pé ìwọ lòdì sí mi ìwọ lòdì sí olùrànlọ́wọ́ rẹ Níbo ni ọba rẹ gbé wà nìsisin yìí kí ó bá à le gbà ọ là Níbo ni àwọn olórí ìlú yín wà, àwọn tí ẹ sọ pé, Fún wa ní ọba àti ọmọ aládé Nítorí èyí nínú ìbínú mi ni mo fún un yín lọ́ba Ninú ìbínú gbígbóná mi, Mo sì mú un kúrò Ẹ̀bi Éfúráímù ni a tí ko jọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀ Ìrora bí obìnrin tó fẹ́ bímọ ti dé bá a Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọmọ tí kò lọ́gbọ́n Nígbà tí àsìkò tó, ó kọ̀ láti jáde síta láti inú Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú Ikú, àjàkálẹ̀-àrùn rẹ dà Isà okú, ìparun rẹ dà Èmi kò ní ṣàánú mọ́ Bí ó tilẹ̀ gbilẹ̀ láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀ afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yóò wá, Yóò fẹ́ wá láti inú asálẹ̀ orísun omi rẹ̀ yóò gbẹ kànga rẹ̀ yóò gbẹ pẹ̀lú olè yóò fọ́ ilé ẹrù àti gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀ Ará Sámáríà gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run wọn Wọn ó ti ipa idà ṣubú a ó fọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, A ó sì la àwọn aboyún wọn nínú A Mú Ísírẹ́lì Padà Bọ́ Sípò Yípadà ìwọ Ísírẹ́lì sí Olúwa Ọlọ́run rẹ Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ! Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́, Kí ẹ sì yípadà sí Olúwa Ẹ sọ fún un pé Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá kí o sì fi oore ọ̀fẹ́ gbà wá, kí àwa kí ó lè fí ètè wa sán-an fún ọ Asíríà kò le gbà wá là A kò ní í gorí ẹsin ogun A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé Àwọn ni òrìṣà wa sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn aláìní baba tí ń rí àánú Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn, Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ ọ wọn Èmi o dàbí ìrì sí Ísírẹ́lì wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì yóò sì ta gbòngbò kédárì ti Lébánónì Àsẹ̀sẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà, Didan ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi ólífì Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi sídà ti Lébánónì Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀ Yóò rúwé bi ọkà Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà, òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lébánónì Ìwọ Éfúráímù Kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà Èmi ó daba! lóhùn, èmi o sì ṣe ìtọ́jú rẹ Mo dàbí igi tó ń fi gbogbo ìgbà tutù, èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi Ta ni ọlọgbọ́n Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí Ta a ní ó mọ̀ Òun yóò ní ìmọ̀ wọn Tí tọ́ ni ọ̀nà Olúwa àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ nìyóò kọsẹ̀ nínú wọn Ẹ̀sùn Tí A Fi Kan Ìyàwó Aláìṣòótọ́ Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, Ènìyàn mi, kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ Àánú Ẹ bá ìyáa yín wí, ẹ bá a wí, nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi, Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀ Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀ àti àìsòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀ Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòòhò Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ lá ìwọṣọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a bí i Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀, Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀ Èmi yóò sì fi òùngbẹ gbẹ ẹ́ Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́ Ìyá wọn jẹ́ aláìsòótọ́ ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú Ó wí pé, èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi, tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi, aṣọ oríṣìíríṣìí, òróró àti ohun mímu lẹ́yìn Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn Yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn Nígbà náà ni yóò sọ pé, Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́ nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsìnyí lọ Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni àti ẹni tó fún un ní ọkà, ọtí-wáìnì tuntun àti òróró ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọpọ̀ Èyí tí wọ́n lò fún Báálì Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n, èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀ Èmi yóò sì gba ìrun àgùntàn irun àgùtàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà mo ti fifun un láti bo ìhòòho rẹ̀ Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi Èmi yóò mú gbogbo ayọ̀ rẹ̀ wá sí òpin àjọ̀dún ọdọọdún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀, ọjọ́ ìsinmi, àti gbogbo àwọn àṣàyàn ọdún rẹ̀ Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run, Èyí tí ó pè ní èrèe rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn Olólùfẹ́ rẹ̀, Èmi yóò sọ wọ́n di igbó, àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run Èmi yóò jẹ́ ẹ́ níyà fún gbogbo ọjọ́ tó fi jo tùràrí sí Báálì tí ó fi òrùka àti ohun ọ̀ṣọ́ wọ ara rẹ̀ tán, tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ Ṣùgbọ́n ó gbàgbé èmi, ni Olúwa wí Nítorí náà, èmi yóò tàn án Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀ Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀ Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un, Èmi yóò fi àfonífojì Ákórì ṣe ilẹ̀kùn ìrètí fún un Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Éjíbítì Yóò si ṣe ní ọjọ́ náà Ìwọ yóò pè mí ní Ọkọ mi Ìwọ kò sì ní pè mí ní olúwa à mi mọ́, ni Olúwa wí Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Báálì kúrò lẹ́nu rẹ̀ ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Báálì pè mọ́ Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú fún wọn àti àwọn ẹranko ìgbẹ́ àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀ Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́ Ọrun, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní ìsòtítọ́ ìwọ yóò sì mọ Olúwa Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà ni Olúwa wí Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn Ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró lóhùn Gbogbo wọn ó sì dá Jésírẹ́lì lóhùn Èmi ó sì gbìn-ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri àànú Gbà Èmi yóò sọ fún àwọn tí Kì í ṣe ènìyàn mi pé, Ẹ̀yin ni ènìyàn mi àwọn náà yóò sì wí pé, Ìwọ ni Ọlọ́run mi   Hósíà Bá Ìyàwó Rẹ Làjà Olúwa sì wí fún mi pé, Lọ, fi ìfẹ́ hàn sí ìyàwó rẹ̀ padà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlòmíràn ti fẹ́ ẹ, tí òun sì tún jẹ́ alágbèrè Fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ṣe fẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tẹ́lé àwọn òrìṣà tí ó sì fẹ́ràn oúnjẹ tí àwọn aláìkọlà yà sọ́tọ̀ Nítorí náà, mo sì rà á padà ní ṣékélì fàdákà mẹ́ẹ̀dógún àti Ómírì kan àti lẹ́tíkì báálì kan Mo sì sọ fún un pé, Ìwọ gbọdọ̀ máa gbé pẹ̀lú mi fún ọjọ́ pípẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè mọ́ tàbí kí o fẹ́ ọkùnrin mìíràn, èmi náà yóò sì gbé pẹ̀lú ù rẹ Nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láì ní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́ láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò padà láti wá Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dáfídì ọba wọn Wọn yóò sì wá síwájú Olúwa pẹ̀lú ẹ̀rù, wọn ó sì jọ̀wọ́ ara wọn fún Olúwa àti ìbùkún rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn Ẹ̀sùn Tí Ọlọ́run Fi Kan Ísírẹ́lì Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùn kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́ Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà Afi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn olè jíjà àti panṣágà Wọ́n rú gbogbo òfin, ìtàjẹ̀sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀sílẹ̀ Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú omi ló ń kú Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá, kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹ̀nìkéjì nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà Ẹ ń ṣubú lọ́sàn-án àti lóru àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lúu yín Èmi ó pa ìyá rẹ run Àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀ Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀ Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi nítorí pé ẹ ti kọ òfìn Ọlọ́run yín sílẹ̀ Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú Wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀sẹ̀ àwọn ènìyàn mi Wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn Yóò wá ṣe gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà rí Èmi ó jẹ gbogbo wọn níyà nítorí ọ̀nà wọn Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó Wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i, nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwa sílẹ̀ Wọ́n sì ti fi ara wọn fún àgbèrè, wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́ àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi Ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn sìnà wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn Wọ́n ń rúbọ lórí àwọn òkè ńlá, Wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeré Lábẹ́ igi óákù, àti igi pópúlárì àti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dára Nítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrè àti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín níyà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín, nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́ Wọ́n sì ń rúbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ilé òrìṣà Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Ísírẹ́lì Ìdájọ́ yìí wà fún un yín Ẹ má ṣe jẹ́ kí Júdà di ẹlẹ́bi Ẹ má ṣe lọ sí Gílígálì Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Bẹti-Áfénì Ẹ má sì búra pé, Bí Olúwa ti wà láàyè nítòótọ́! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe agídí bí alágídí ọmọ màlúù Báwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọn bí àgùntàn ní pápá oko tútù Éfúráímù ti darapọ̀ mọ́ òrìṣà Ẹ fi sílẹ̀! Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tán wọ́n tún tẹ̀ṣíwájú nínú àgbèrè àwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ Ìjì ni yóò gbá wọn lọ Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn Ìdájọ́ Ń Bọ̀ Lórí Ísírẹ́lì Àti Júdà Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà! Ẹ fetí sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì! Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba! Ìdájọ́ yìí kàn yín Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mísípà Àwọ̀n ti a nà sìlẹ̀ lórí Tábórì Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn Gbogbo wọn ni èmi ó bá wí, Mo mọ ohun gbogbo nípa Éfúráímù Ísírẹ́lì kò sì pamọ́ fún mi Éfúráímù, ní báyìí ó ti di alágbèrè Ísírẹ́lì sì ti díbàjẹ́ Iṣe wọn kò gbà wọ́n láàyè láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn Ẹ̀mí àgbèrè wà láàrin wọn kò sì mọ Olúwa Ìgbéraga Ísírẹ́lì ń jẹ́rìí lé wọn Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti Éfúráímù pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn Júdà náà sì kọṣẹ̀ pẹ̀lú wọn Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa , wọn kò ní rí i, ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrin wọn Wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí Olúwa wọ́n sì bí àwọn ọmọ àlè Nísinsìn yìí, ọdún oṣù tuntun wọn, ni yóò pa wọn run pẹ̀lú pín wọn Fọn fère ní Gíbíà, kí ẹ sì fun ipè ní Rámà Ẹ pariwó ogun ní Bẹti-Áfélì máa wárìrì, ìwọ Bẹ́ńjámínì Éfúráímù yóò di ahoro ní ọjọ́ ìbáwí láàrin àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì Mo sọ ohun tí ó dájú Àwọn olórí Júdà dàbí àwọn tí í máa yí òkúta ààlà kúrò Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí bí ìkún omi A ni Éfúráímù lára, A sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́ nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Éfúráímù Mo sì dàbí ìdin sí ara Júdà Nígbà ti Éfúráímù ri àìsàn rẹ̀, tí Júdà sì rí ojú egbò rẹ̀ ni Éfúráímù bá tọ ará Síríà lọ, ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́ ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Éfúráímù, bí i kìnnìún ńlá sí ilé Júdà Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ Èmi ó gbé wọn lọ, láì sí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀ Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi wọn yóò sì wá ojú mi nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi Àìronúpìwàdà Ísírẹ́lì Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣùgbọ́n yóò mú wa lára dá Ó ti pa wá lára ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀ Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ṣíwájú láti mọ̀ ọ́ Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ, Yóò jáde Yóò tọ̀ wá wá bí òjò bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀ Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Éfúráímù Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Júdà Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùku òwúrọ̀ bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi Ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín Nítorí pé mo fẹ́ àánú, kì í ṣe ẹbọ àti ìmọ́ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ Bí i Ádámù, wọ́n da májẹ̀mú wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí mi níbẹ̀ Gílíádì jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́ Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùbá de àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀ tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣékémù, tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú Mo ti rí ohun tó bani lẹ́rù ní ilé Ísírẹ́lì Níbẹ̀ Éfúráímù, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè Ísírẹ́lì sì di aláìmọ́ Àti fún ìwọ, Júdà A ti yan ọjọ́ pẹ̀lú ìkórè rẹ Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà, Nígbà tí èmi ìbá mú Ísírẹ́lì láradá Ẹ̀ṣẹ̀ Éfúráímù ń farahàn ìwà búburú Ṣamáríà sì ń hàn síta Wọ́n ń ṣe èrú àwọn olè ń fọ́ ilé àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo rántí gbogbo ìwà búburú wọn Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátapáta wọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn, àti inú ọmọ aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn Alágbèrè ni gbogbo wọn wọ́n gbóná bí ààrò àkàrà tí o dáwọ́ kíkọná dúró, lẹ́yìn ìgbà tí o ti pò iyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wa wáìnì mú ara àwọn ọmọ aládé gbóná ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́ Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààrò wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkísí, ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òru ó sì bú jáde bí ọ̀wọ́ iná ní òwúrọ̀ Gbogbo wọn gbóná bí ààrò wọ́n pa gbogbo olórí wọn run, gbogbo ọba wọn si ṣubú kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí Éfúráímù ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà Éfúráímù jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run ṣùgbọ́n kò sì mọ̀, Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsíi Ìgbéraga Ísírẹ́lì ń jẹ́rìí sí i ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a Éfúráímù dàbí àdàbà tó rọrùn láti tàn jẹ àti aláìgbọ́n tó wá ń pé Éjíbítì nísinsìn yìí tó sì tún ń padà lọ si Ásíríà Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀ Èmi nà wọ́n bí ìjọ ènìyàn wọn ti gbọ́ Ègbé ní fún wọn, nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun wà lórí wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi! Èmi yóò rà wọ́n padà Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn, Ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùn réré ẹkún lórí ibùsùn wọn Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára, ṣíbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi Wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gá ògo Wọ́n dàbí ọrun tí ó wà fún ìtànjẹ́ Àwọn aṣíwájú wọn yóò ti ipa idà ṣubú nítorí irúnú ahọ́n wọn Torí èyí, wọn ó fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ní ilẹ̀ Éjíbítì Ísírẹ́lì Yípadà Kúrò Ní Ọ̀nà Ọlọ́run rẹ̀ Fi ìpè sí ẹnu rẹ! Ẹyẹ igún wà lórí ilé Olúwa nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú, wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi Ísírẹ́lì kígbe pè mí Áà! Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́! Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀ ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀ Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi wọ́n yan ọmọ aládé láì si ìmọ̀ mi nibẹ̀ Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe ère fún ara wọn, kì a ba le ké wọn kúrò Ọmọ-mààlu rẹ ti ta ọ́ nù ìwọ Ṣamáríà! Ju ère tí o gbẹ́ nù Ìbínú mi ń ru sí wọn yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan Ísírẹ́lì ni wọ́n ti wá! Ère yìí—agbẹ́gilére ló ṣe é Àní ère Samáríà, ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ Wọ́n gbin afẹ́fẹ́ wọ́n sì ká ìjì Igi ọkà kò lórí, kò sì ní mú oúnjẹ wá Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà àwọn àlejò ni yóò jẹ A ti gbé Ísírẹ́lì mì, Báyìí, ó sì ti wà láàrin àwọn orílẹ̀ èdè bí ohun èlò tí kò wúlò Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Síríà gẹ́gẹ́ bí ẹhànnà kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń rìn kiri Éfúráímù ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárin orílẹ̀ èdè Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsìn yìí Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù lọ́wọ́ ìnílára ọba alágbára Nítorí Éfúráímù ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn Ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì Wọ́n ń rúbọ tí wọ́n yàn fún mi, wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀ Ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn yóò sì jẹ wọ́n níyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn Wọn yóò padà sí Éjíbítì Nítorí Ísírẹ́lì ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀ Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀ Júdà ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀ ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run Ìdájọ́ Fún Ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì Má ṣe yọ̀, ìwọ Ísírẹ́lì má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀ èdè yòókù Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìsòótọ́ si lọ́run yín Ẹ fẹ́ràn láti gbowó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ilẹ̀ ìpàkà Àwọn ilé ìpàkà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀ Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa Éfúráímù yóò padà sí Éjíbítì Yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ̀ ní Ásíríà Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́ Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọn kò ńi wá sí orí tẹ́ḿpìlì Olúwa Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àsè yín tí a ti yàn ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun Éjíbítì yóò kó wọn jọ, Mémúfísì yóò sì sin wọ́n Ibi ìsọjọ̀ sílífa wọn ni yèrèpè yóò jogún, Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn Ẹ̀gún yóò sì bo gbogbo àgọ́ wọn Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀ Àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé Jẹ́ kí Ísírẹ́lì mọ èyí Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀ A ka ẹni ìmísí sí asínwín Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ni olùṣọ́ ọ Éfúráímù Ṣíbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀ Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gíbíà Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn yóò sì jẹ wọ́n níyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn Nígbà tí mo rí Ísírẹ́lì, Ó dàbí ìgbà tí ènìyàn rí èso àjàrà ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ Nígbà tí mo rí àwọn baba yín Ó dàbí ìgbà tí ènìyàn rí àkọ́so èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Baali-Péórì Wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni wọ́n di aláìmọ́ bí ohun tí wọ́n fẹ́ràn Ògo Éfúráímù yóò fò lọ bí ẹyẹ kò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn Ègbé ni fún wọn, nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn! Mo rí Éfúráímù bí ìlú Tírúsì tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára ṣùgbọ́n Éfúráímù yóò kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn Fún wọn, Olúwa ! Kí ni ìwọ yóò fún wọn Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́ àti ọyàn gbígbẹ Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gílígálì Mo kórìírà wọn níbẹ̀, Nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́ ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn Éfúráímù ti rẹ̀ dànù Gbogbo rẹ̀ sì ti rọ, kò sì so èso, Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí pé wọn kò gbọ́ràn sí i wọn yóò sì di alárìnkiri láàrin àwọn orílẹ̀ èdè Ọlọ̀tẹ̀ Orílẹ̀ Èdè Kan Ìran sí Júdà àti Jérúsálẹ́mù èyí tí Àìṣáyà ọmọ Ámọ́sì rí ní àsìkò ìjọba Hùṣáyà, Jótamù, Áhásì àti Heṣekáyà àwọn ọba Júdà Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé! Nítorí Olúwa ti sọrọ̀ Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà, Ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi Màlúù mọ olówó rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀, ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì kò mọ̀, òye kò yé àwọn ènìyàn mi Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù, Ìran àwọn aṣebi, àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́! Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀ wọn ti gan Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì, wọn sì ti kẹ̀yìn sí i Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́ Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́, gbogbo ọkan yín sì ti pòrúúru Láti àtẹ́lẹṣẹ̀ yín dé àtàrí yín kò sí àlàáfíà rárá, àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa àti ojú egbò, tí a kò nùnù tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró Orílẹ̀-èdè yín dahoro, a dáná sun àwọn ìlú yín, oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ run lójú ara yín náà, ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tí àwọn àjèjì borí rẹ̀ Ọmọbìnrin Ṣíónì ni a fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà, gẹ́gẹ́ bí àbá nínú oko ẹ̀gúsí, àti bí ìlú tí a dótì Àyàfi bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun bá sẹ́ díẹ̀ kù fún wà, a ò bá ti rí bí Sódómù, a ò bá sì ti dàbí Gòmórà Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa , ẹ̀yin aláṣẹ Sódómù, tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn Gòmórà! Ọpọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi ni Olúwa wí Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa, Èmi kò ní inú dídùn nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn àti ti orúkọ Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi, ta ni ó bèèrè èyí lọ́wọ́ ọ yín, Gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi Ẹ má mú ọrẹ aṣán wá mọ́! Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi, oṣù tuntun, ọjọ́ ọ̀sẹ̀ àti àwọn àpèjọ Èmi kò lè faradà àpèjọ ibi yín wọ̀nyí Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àpèjẹ tí ẹ yà ṣọ́tọ̀ ni ọkàn mi kórìíra Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn, Ó ti sú mi láti máa fara dà wọ́n Nigbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sóke ni àdúrà, Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín, kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà, Èmi kò ni tẹ́ti sí i Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀ Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́ Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi! Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró, kọ́ láti ṣe rere! Wá ìdájọ́ òtítọ́, tù àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú Ṣàtìlẹ́yìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, gbà ẹjọ́ opó rò Ẹ wá ní ìsinsìnyìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàsàrò, ni Olúwa wí Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn, wọn ó sì funfun bí i yìnyín, bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀, wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n-òwú Tí ó bá tinú un yín wá tí ẹ sì gbọ́ràn, ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀, idà ni a ó fi pa yín run Nítorí ẹnu Olúwa la ti sọ ọ́ Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè! Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí, òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí ṣùgbọ́n báyìí o àwọn apànìyàn! Sílífà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́, ààyò wáìnì rẹ la ti bomi là Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín, akẹgbẹ́ àwọn olè, gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, ẹjọ́ opó kì í sìí dé iwájú wọn Nítorí náà ni Olúwa , Olúwa àwọn ọmọ-ogun Alágbára kanṣoṣo tí Ísírẹ́lì sọ wí pé Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi n ó sì gbẹ̀ṣan lára àwọn ọ̀tá mi Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ, èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù, n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀sípò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́, àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́ A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Ṣíhónì padà, àti àwọn tí ó ronú pìwàdà pẹ̀lú òdodo Ṣùgbọn àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó pa run Àwọn tí ó bá sì kọ Olúwa sílẹ̀ ni yóò ṣègbé Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́ èyí tí ẹ ní inú dídùn sí a ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìí tí ẹ ti yàn fúnra yín Ẹ ó sì dàbí igi óákù tí ewé rẹ̀ tí, tàbí bí ọgbà tí kò ní omi Alágbára ọkùnrin náà yóò sì dàbí lẹ́ù iṣẹ́ rẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ́-iná, àwọn méjèèjì ni yóò jóná papọ̀, láì sí ẹni tí yóò lè pa iná yìí Ìdájọ́ Ọlọ́run Lórí Ásíríà Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn àti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi, wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn Wọ́n sì ń ja àwọn aláìní lólè Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirò nígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jínjìn wá Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrin àwọn ìgbèkùn tàbí kí o ṣubú sáàrin àwọn tí a pa Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò, ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè Ègbé ni fún àwọn ará Ásíríà, ọ̀gọ ìbínú mi, ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà! Mo rán an sí orílẹ̀ èdè aláìní Ọlọ́run Mo dojúu rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó múmi bínú láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun láti tẹ̀mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe, èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn èrò rẹ̀ ni láti parun, láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè Kì í haá ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi ni Olúwa wí Kì í ha á ṣe pé Kálínò dàbí i Káṣẹ́míṣì Hámátì kò ha dàbí i Ápádì, àti Ṣamáríà bí i Dámásíkù Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú, Ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jérúsálẹ́mù àti Ṣamáríà lọ Èmi kì yóò a bá Jérúsálẹ́mù wí àti àwọn ère rẹ̀   Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Ṣamáría àti àwọn ère rẹ̀ Nígbà tí Olúwa bá parí iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Ṣíhónì àti Jérúsálẹ́mù, yóò sọ wí pé, Èmi yóò fi ìyà jẹ Ásíríà nítoríi gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojúu rẹ̀ Nítorí ó sọ pé  Pẹ̀lú agbára ọwọ́ọ̀ mi ni mo fi ṣe èyí àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀ èdè kúrò, Mo sì ti kó ìṣúra wọn Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn Bí ènìyàn tií tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ọ̀ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè Bí ènìyàn tii kó ẹyin tí a kọ̀ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀ èdè kò sí èyí tí ó fapálupá, tàbí kí ó ya ẹnu láti dún   Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í, tàbí kí ayùn fọnnu sí ẹni tí ó ń lò ó Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè, tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi Nítorí náà, ni Olúwa , Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò rán àrùn ìrẹ̀dànù sórí àwọn akíkanjú jagunjagun, lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun Ìmọ́lẹ̀ Ísírẹ́lì yóò di iná, ẹni Mímọ́ an wọn ahọ́n iná, ní ijọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n Gbogbo ẹwà igbóo rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátapáta, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó sàìṣàn ti í ṣòfò dànù Àwọn igi tí yóò kù nínú igbóo rẹ̀ yóò kéré níye, tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀ Ní ijọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Ísírẹ́lì Àwọn tí ó yè ní ilée Jákọ́bù kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà tí ó lùwọ́n bolẹ̀ ṣùgbọ́n yóò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jákọ́bù yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn an rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì dàbí yanrìn ní òkun, ẹni díẹ̀ ni yóò padà A ti pàṣẹ ìparun à kún wọ́ sílẹ̀ àti òdodo Olúwa , Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú-un ṣẹ, ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ náà Nítorí náà, báyìí ni Olúwa , Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Ṣíhónì, Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Ásíríà, tí ó ń fi ọ̀pá lù yín, tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tìyín bí Éjíbítì ti ṣe Láìpẹ́, ìbínú mi síi yín yóò wá sí òpin n ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n, fún ìparun wọn Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Mídíánì ní òkè Órébù, yóò sì gbé ọ̀páa rẹ̀ lé orí omi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Éjíbítì Ní ọjọ́ náà, a ó gbé ẹrùu wọn kúrò ní èjìká a yín, àti àjàgà a wọn kúrò ní ọrùn un yín a ó fọ́ àjàgà náà, nítorí pé ẹ̀yin ó ti sanra Wọ́n wọ Áíyátì, Wọ́n gba Mígírónì kọjá Wọ́n kó nǹkan pamọ́ sí Mísímásì Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé, Àwa ó tẹ̀dó sí Gébà lóru yìí Rámà mì tìtì Gíbíà ti Ṣọ́ọ̀lù sá lọ Kígbe ṣókè, ìwọ ọmọbìnrin Gálímù Dẹtísílẹ̀, Ìwọ Láíṣà Òpè Ánátótì Mádíménà ti fẹṣẹ̀ fẹ́ ẹ Àwọn ènìyàn Gébímù ti farapamọ́ Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nóbù wọn yóò kan sáárá, ní òkè ọmọbìnrin Ṣíhónì ní òkè Jérúsálẹ́mù Wò ó, Olúwa , Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò kán ẹ̀ka náà sọnù pẹ̀lú agbára Àwọn igi ọlọ́lá ni a ó gé lulẹ̀ Àwọn tí ó ga gogoro ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké, Lẹ́bánónì yóò ṣubú níwájú Alágbára náà Ẹ̀ka Láti Ọ̀dọ̀ Jéésè Èhíhù kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jéésè, láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa Òun yóò sì ní inúdídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojúu rẹ̀ rí, tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etíi rẹ̀ gbọ́, Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní, pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu fún àwọn aláìní ayé Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀, pẹ̀lú ooru ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀ àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ ká Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé, àmọ̀tẹ́kùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́ ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀ ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n Màlúù àti béárì yóò máa jẹun pọ̀, àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀, kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká, Ọmọdé yóò ki ọwọ́ọ rẹ̀ bọ ìtẹ́ẹ paramọ́lẹ̀ Wọn kò ní ṣeni lọ́ṣẹ́ tàbí panirun ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa gẹ́gẹ́ bí omi ti í bo òkun Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jéésè yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àṣíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀ èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Ásíríà wá, láti ìsàlẹ̀ Éjíbítì àti Òke Éjíbítì, láti Kúṣì, láti Élámù láti Babilóníà, láti Hámátì àti láti àwọn erékùṣù inú òkun Òun yóò gbé àṣíá sókè fún àwọn orílẹ̀ èdè, yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Ísírẹ́lì jọ, yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Júdà tí a ti fọ́n káàkiri jọ, láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé Owú jíjẹ Éfáímù yóò pòórá, àwọn ọ̀tá Júdà ni a ó ké kúrò, Éfáímù kò ní jowúu Júdà, tàbí Júdà kó dojú kọ Éfáímù Wọn yóò dìgbòlu àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Fílísítíà ni apá ìwọ̀ oòrùn, wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn ènìyàn apá ìlà oòrùn Wọn yóò gbé ọwọ́ọ wọn lé Édómù àti Móábù, àwọn ará Ámónì yóò sì di ìwẹ̀fàa wọn Olúwa yóò sọ di gbígbé àyasí òkun Éjíbítì, pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ọ rẹ̀, kọjá lórí odò Éúfírétì Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn yóò máa là á kọjá pẹ̀lúu bàtà Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù tí ó kù sílẹ̀ ní Ásíríà, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n gòkè láti Éjíbítì wá Orin Ìyìn Ní ọjọ́ náà ìwọ ó wí pé Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀ ìwọ sì ti tù mí nínú Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi, Èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù Olúwa , Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi, òun ti di ìgbàlà mi Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi láti inú un kànga ìgbàlà Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé Fi ọpẹ́ fún Olúwa , ké pe orúkọ rẹ̀, Jẹ́ kí ó di mímọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, ohun tí ó ti ṣe kí o sì kéde pé a ti gbé orúkọ rẹ̀ ga Kọ orin sí Olúwa , nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo, jẹ́ kí èyí di mímọ̀ fún gbogbo ayé Kígbe ṣókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ṣíhónì, nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kanṣoṣo ti Ísírẹ́lì láàrin yín Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Sí Bábílónì Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Bábílónì èyí tí Àìṣáyà ọmọ Ámọ́sì rí Gbé àṣíá ṣókè ní orí òkè gbẹrẹfu, kígbe sí wọn, pè wọ́n láti wọlé sí ẹnu ọ̀nà àwọn Bọ̀rọ̀kìnní Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi, mo ti pe àwọn jagunjagun mi láti gbé ìbínú mi jáde àwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè, gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn Gbọ́, ìdàrúdàpọ̀ láàrin àwọn ìjọba, gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀ èdè! Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ àwọn jagunjagun fún ogun Wọ́n wá láti ọ̀nà jínjìn réré, láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá Olúwa pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú un rẹ̀— láti pa gbogbo orílẹ̀ èdè náà run Pohùnréré, nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́tòsí, yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ, ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú, ìrora àti ìpayínkeke yóò dì wọ́n mú, wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí Ẹnìkín-ín-ní yóò wo ẹnìkejìi rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà ojú wọn á sìgbinájẹ Kíyèsí i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú gbígbóná— láti sọ ilẹ̀ náà dahoro àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú un rẹ̀ run Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run ati ìkójọpọ̀ wọn kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ òòrùn yóò di òkùnkùn àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀, àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀ Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọn ju ojúlówóo wúrà lọ, yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà ófírì lọ Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀ láti ọwọ́ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná an rẹ Gẹ́gẹ́ bí èkùlù tí à ń dọdẹ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí a bá gbámú ni a ó wọ́ nílẹ̀ tuurutu, gbogbo àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò ti ipa idà kú Àwọn mọ̀jèsín wọn ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn, gbogbo ilẹ̀ wọn ni a ó kó àwọn aya wọn ni a ó sì bá dàpọ̀ Kíyèsí i, èmi yóò ru àwọn Mẹ́dísì sókè sí wọn, àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀ wọn kò ní ṣàánú àwọn mọ̀jèsín tàbí kí wọn síjú àánú wo àwọn ọmọdé Bábílónì, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba ògo ìgbéraga àwọn ará Bábílónì ni Ọlọ́run yóò dojúrẹ̀ bolẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Sódómù àti Gòmórà A kì yóò sì gbé ibẹ̀ mọ́ tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran Árábù kan yóò fi àgọ́ rẹ lélẹ̀ níbẹ̀, Olùsọ́ àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn ohun abẹ̀mí aṣálẹ̀ ni yóò gbé bẹ̀, àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn, níbẹ̀ ni àwọn òwììwí yóò máa gbé níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́-igbó yóò ti máa bẹ́ kiri Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn, àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn Àsìkò Rẹ Súnmọ́ Etílé, Àwọn Ọjọ́ Rẹ Ni A Ó Sì Ké Kúrú Olúwa yóò fi àánú hàn fún Jákọ́bù, yóò tún Ísírẹ́lì yàn lẹ́ẹ̀kan síi yóò sì fi ìdíi wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóò sì fọwọ́ṣowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilée Jákọ́bù Àwọn orílẹ̀ èdè yóò gbà wọ́n wọn yóò sì mú wọn wá sí àyèe wọn Ilé Ísírẹ́lì yóò gba àwọn orílẹ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin ní ilẹ̀ Olúwa Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn wọn yóò sì jọba lórí àwọn amúnisìn wọn Ní ọjọ́ tí Olúwa yóò fi ìtùra fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà, ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Bábílónì pé Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin! Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí! Olúwa ti dá ọ̀pá ìkà náà, ọ̀pá àwọn aláṣẹ, èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀ pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró, nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà, wọ́n bú sí orin Pẹ̀lú pẹ̀lù àwọn igi Páínì àti àwọn igi kédárì ti Lẹ́bánónì ń yọ̀ lóríì rẹ ó wí pé, Níwọ̀n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí, kò sí alagi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀ Ibojì tí ó wà ní ìṣàlẹ̀ ni a ru sókè láti pàdé rẹ ní àpadàbọ̀ rẹ̀ ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ ṣókè láti wá kí ọ gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ẹ wọn gbogbo àwọn tí ó jọba lórí àwọn orílẹ̀ èdè Gbogbo wọn yóò dáhùn, wọn yóò wí fún ọ wí pé, Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ìwọ náà ti dàbí wa Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì, pẹ̀lú ariwo àwọn hápù rẹ, àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀ Báwo ni ìwọ ṣe ṣubúlulẹ̀ láti ọ̀run wá, ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà! A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé Ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀ èdè ba rí! Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé, Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run, Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpèjọ ní ṣónṣó orí òkè mímọ́ Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọ̀sánmọ̀ Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá ògo Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọ lọ sí ìṣàlẹ̀ ọ̀gbun Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ, wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì Ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀, tí ó dojú àwọn ìlú ńlá ńlá bolẹ̀ tí kò sì jẹ́ kí àwọn ìgbèkùn padà sílé Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀ èdè ni a tẹ́ sílẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀ Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀ sílẹ̀, àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀, àwọn tí idà ti gún, àwọn tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀, A kò ní sin ọ́ pẹ̀lúu wọn, nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́ o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ Ìran àwọn ìkà ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́ Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńláa wọn, wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀ kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlúu wọn Èmi yóò dìde ṣókè sí wọn, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Bábílónì àti àwọn tí ó sálà, àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀, ni Olúwa wí Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwí àti sí irà Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra, Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí, àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró Èmi yóò run Ásíríà ní ilẹ̀ mi, ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀ Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi, ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìkáa wọn Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé, èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète, ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Áhásì kú Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Fílístínì, pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá láti ibi gbòngbò ejò náà ni pamọ́lẹ̀ yóò ti hù jáde, èṣo rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tíí jóni Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko, àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu Ṣùgbọ́n gbòǹgbòo rẹ ni èmi ó fi ìyàn parun, yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò Kígbe, Ìwọ ẹnu ọ̀nà! Pariwo, Ìwọ ìlú! Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Fílístínì! Kurukuru èéfín kan ti Àríwá wá, kò sì sí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn Kí ni ìdáhùn tí a ó fún agbẹnusọ orílẹ̀ èdè náà Olúwa ti fi ìdí Ṣíhónì kalẹ̀, àti nínú un rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a ti pọ́nlójú yóò ti rí ààbò o wọn Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Móábù A pa Árì run ní Móábù, òru kan kí a paárun! A pa Kárì run ní Móábù, òru kan kí a paárun! Díbónì gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlìi rẹ̀, sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti ṣunkún, Móábù pohùnréré lórí Nébónì àti Médíbà Gbogbo orí ni a fá gbogbo irungbọ̀n ni a gé dànù Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà, ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede àkójọ wọ́n pohùnréré, Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún Hẹ́ṣíbónì àti Élíálè ké ṣóde, ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jáhásì Nítorí náà ni àwọn ọmọ ogun Móábù ṣe kígbe tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ́sì Ọkàn mi kígbe lórí Móábù àwọn ìṣáǹṣá rẹ sálà títí dé Ṣóárì, títí fi dé Égílátì Ṣẹ́líṣíyà Wọ́n gòkè lọ títí dé Lúhítì wọ́n ń ṣunkún bí wọ́n ti ń lọ, Ní òpópónà tí ó lọ sí Hórónáímù wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn Gbogbo omi Nímírímù ni ó ti gbẹ àwọn koríko sì ti gbẹ, gbogbo ewéko ti tán ewé tútù kankan kò sí mọ́ Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní tí wọ́n sì tòjọ wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lóríi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò pópúlárì Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ Móábù ìpohùnréré wọn lọ títí dé Ẹgíláémù, igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Élímù Omi Dímónì kún fún ẹ̀jẹ̀, ṣíbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dímónì— kìnnìún kan wá ṣórí àwọn ìṣáǹṣá Móábù àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, Láti Ṣẹ́là, kọjá ní ihà, lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Ṣíhónì Gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ẹ̀rẹ̀ǹbalẹ̀ tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Móábù ní àwọn ọmọdo Ánónì Fún wa ní ìmọ̀ràn ṣe ìpinnu fún wa Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru— ní ọ̀sán gangan Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́, má ṣe tú àwọn aṣàtìpó fó Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Móábù gbé pẹ̀lúù rẹ, jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun Aninilára yóò wá sí òpin, ìparun yóò dáwọ́ òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀ Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀, ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lóríi rẹ̀— ọ̀kan láti ilé Dáfídì wá Ẹni nní ti ìdájọ́ ń wá ẹ̀tọ́ tí ó sì fi ìyára wá ohun tí í ṣe òdodo Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù— Wábiwọ́sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge, gààrùu rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀— ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo Nítorí náà ni àwọn ará Móábù pohùnréré wọ́n jùmọ̀ pohùnréré lórí Móábù Ṣunkún kí o sì banújẹ́ fún àwọn ọkùnrin ìlú Hárésétì Gbogbo pápá-oko Héṣíbónì ti gbẹ, bákan náà ni àjàrà Ṣíbínà rí Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀ èdè wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀, èyí tí ó ti fà dé Jáṣérì ó sì ti tàn dé agbègbè aṣálẹ̀ Àwọn èhu rẹ̀ fọ́n jáde ó sì lọ títí ó fi dé òkun Nítorí náà mo ṣunkún, gẹ́gẹ́ bí Jáṣérì ṣe ṣunkún, fún àwọn àjàrà Ṣíbínà Ìwọ Hẹ́ṣíbónì, Ìwọ Élíálẹ̀, mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú! Igbe ayọ̀ lórí àwọn èṣo pípọ́n rẹ àti lórí ìkóórè èyí tí o ti mọ́wọ́dúró Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò nínú ọgbà-igi eléso rẹ kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí kígbe nínu ọgbà-àjàrà ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí, nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe Ọkàn mi kérora fún Móábù gẹ́gẹ́ bí i hápù, àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Háréṣétì Nígbà tí Móábù farahàn ní ibi gíga rẹ̀, ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán Nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà òfo ni ó já sí Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa Móábù Ṣùgbọn ní àkókò yìí Olúwa wí pé Láàrin ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, Ògo Móábù àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó ṣálà nínú un rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ìmọ̀ Kan Sí Dámásíkù Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Dámásíkù Kíyèsíí, Dámásíkù kò ní jẹ́ ìlú mọ́ ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn Àwọn ìlú Áróérì ni a ó kọ̀ sílẹ̀ fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn ṣíbẹ̀, láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Éfáímù, àti agbára ọba kúrò ní Dámásíkù àwọn àsẹ́ku Árámù yóò dá gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Ísírẹ́lì, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ní ọjọ́ náà ni ògo Jákọ́bù yóò ṣá ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkóórè kó àwọn irúgbìn tí ó dúró jọ tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀— àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní àfonífojì ti Réfémù Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi ólífì, tí èṣo ólífì méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ, mẹ́rin tàbí márùn ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù, ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójúsókè sí Ẹlẹ́dàá wọn wọn yóò sì síjú wo Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́, èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ọ wọn, wọn kò sì ní kọbi ara sí òpó Áṣérà mọ́ tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára wọn, tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò dàbí ilẹ̀ tí a dà sílẹ̀ kó di ìgbòrò Gbogbo wọn yóò sì di ahoro Ẹ ti gbàgbé Ọlọ́run Olùgbàlà yín ẹ kò sì rántí àpáta náà, àní odi agbára yín Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àsàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hú jáde, àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n ẹ mú kí wọ́n rúdí, ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìkóórè kò ní mú nǹkan wá ní ọjọ́ àrùn àti ìrora tí kò gbóògùn Kíyèsii, ìrunú àwọn orílẹ̀ èdè— wọ́n ń runú bí ìgbì òkun! Kíyèsii, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò, nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n ṣálọ jìnnà réré, a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè, àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle Ní ihà, ìpayà òjijì! Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́! Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù, àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Sí Kúṣì Ègbé ni fún ìwọ ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́, ní àwọn ipadò Kúṣì, tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí òkun lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi kóríko ṣe Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára, sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀-ara wọn jọ̀lọ̀, sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri, orílẹ̀ èdè aláfojúdi alájèjì èdè, tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé, tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àṣíá kan ṣókè lórí òkè, ẹ ó rí i, nígbà tí a bá fun fèrè kan ẹ ó gbọ́ ọ Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ ẹ́, n ó sì máa wo òréré láti ibùgbé e mi wá, gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànsán òòrùn, gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárin gbùngbùn ìkóórè Nítorí, kí ìkóórè tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìtànná kò sí mọ́, nígbà tí ìtànná di èso tí ó ń pọ́n bọ̀ Òun yóò sì fi ọ̀bẹ ìwẹgi gé àwọ ìsó tuntun kúrò, yóò sì gé àwọn ẹ̀ka tí ó ń gbilẹ̀ lulẹ̀ a sì kó wọn dànù Gbogbo wọn la ó fi lé àwọn jẹran jẹran ẹyẹ lọ́wọ́ lórí òkè àti fún àwọn ẹranko búburú àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣoúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran ara wọn jọ̀lọ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo, orílẹ̀ èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè, ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ— a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Síónì, ibi tí orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbé wà Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Sí Éjíbítì Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Éjíbítì Kíyèsíi, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́sin ó sì ń bọ̀ wá sí Éjíbítì Àwọn ère òrìṣà Éjíbítì wárìrì níwájúu rẹ̀, ọkàn àwọn ará Éjíbítì sì ti domi nínú un wọn Èmi yóò rú àwọn ará Éjíbítì sókè sí ara wọn arákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà, aládúgbò yóò dìde sí aládúgbò rẹ̀, ìlú yóò dìde sí ìlú, ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba Àwọn ará Éjíbítì yóò sọ ìrètí nù, èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀, àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókúsọ̀rọ̀ Èmi yóò fi Éjíbítì lé agbára àwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́, ọba aláìláàánú ni yóò jọba lé wọn lórí, ni Olúwa , Olúwa Alágbára wí Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ, gbogbo ilẹ̀ odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá Àyasí omi yóò máa rùn àwọn odò ilẹ̀ Éjíbítì yóò máa dínkù wọn yóò sì gbẹ Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ, àwọn igi ìpadò Náì pẹ̀lú, tí ó wà ní oríṣun odò Náì Gbogbo oko tí a dá sí ìpadò Náì yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù tí kò sì ní sí mọ́ Àwọn apẹja yóò ṣunkún kíkorò, gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú Náí yóò sì máa rùn Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú àwọn ahunsọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì, gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìṣàn ọkàn yóò ṣe Àwọn oníṣẹ́ Ṣóánì ti di aláìgbọ́n, àwọn ọlọgbọ́n olùdámọ̀ràn Fáráò ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá Báwo ló ṣe lè sọ fún Fáráò pé, Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba ijọ́un Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí Jẹ́ kí wọn fi hàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mímọ̀ ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pinnu lórí Éjíbítì Àwọn oníṣẹ́ Ṣóárì ti di aláìgbọ́n, a ti tan àwọn adarí Méḿfísì jẹ àwọn òkúta igunlé tí í ṣe ti ènìyàn rẹ ti ṣi Éjíbítì lọ́nà Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú un wọn wọ́n mú Éjíbítì ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nínú ohun gbogbo tí ó ń ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n nínú èébì i rẹ̀ Kò sí ohun tí Éjíbítì le ṣe— orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Éjíbítì yóò dàbí obìnrin Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn Ilẹ̀ Júdà yóò da wárìwàrì jó àwọn ará Éjíbítì gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Júdà létíi wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbérò láti ṣe sí wọn Ní ọjọ́ náà ìlú márùn ún ní ilẹ̀ Éjíbítì yóò sọ èdè àwọn ará Kénánì, wọn yóò sì búra àtìlẹyìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárin gbùngbùn Éjíbítì, àti ọ̀wọ̀n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀ Yóò sì jẹ́ ààmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Éjíbítì Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbéjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀ Báyìí ni Olúwa yóò sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Éjíbítì àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba Olúwa gbọ́ Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ oníhóró, wọn yóò jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa wọn yóò sì mú un ṣẹ Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-àrùn kan bá Éjíbítì jà yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn Wọn yóò yípadà sí Olúwa , Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Éjíbítì lọ sí Ásíríà Àwọn ará Ásíríà yóò lọ sí Éjíbítì àti àwọn ará Éjíbítì lọ sí Ásíríà Àwọn ará Éjíbítì àti ará Ásíríà yóò jọ́sìn papọ̀ Ní ọjọ́ náà Ísírẹ́lì yóò di ẹ̀kẹta pẹ̀lú Éjíbítì àti Áṣíríà, àní oríṣun ìbùkún ní ilẹ̀ ayé Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, Ìbùkún ni fún Éjíbítì ènìyàn mi, Áṣíríà iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti Ísírẹ́lì ìní mi Èyí ni ohun tí Àìsáyà ọmọ Ámósì rí nípa Júdà àti Jérúsálẹ́mù Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́ òkè tẹ́ḿpìlì Olúwa ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kékeré lọ, gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sì máa ṣàn sínú un rẹ̀ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn ó si sọ pé Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ sí òkè Olúwa , sí ilé Ọlọ́run Jákọ́bù Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀ Òfin yóò jáde láti Síhónì wá, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jérúsálẹ́mù wá Òun ó ṣe ìdájọ́ láàárin àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀ wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé Orílẹ̀ èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀ èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́ Wá, ẹ̀yìn ará ilée Jákọ́bù ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa Ọjọ́ Olúwa Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, ìwọ ilé Jákọ́bù Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí ó ti ìlà oòrùn wá, wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Fílístínì wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà Ilẹ̀ wọ́n kún fún fàdákà àti wúrà ìṣúra wọn kò sì ní òpin Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn, èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tikálára wọn ti ṣe Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀ ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀, má ṣe dáríjìn wọ́n Wọ inú àpáta lọ, fi ara pamọ́ nínú èrùpẹ kúrò nínú ìpayà Olúwa , àti ògo ọlá ńlá rẹ̀! Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba, Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan nípamọ́ fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga , nítorí gbogbo igi kedari Lẹ́bánónì, tó ga tó rìpó àti gbogbo óákù Báṣánì, nítorí gbogbo òkè gíga ńlá ńlá àti àwọn òkè kéé kèè kéé, fún ilé ìṣọ́ gíga gíga àti àwọn odi ìdáàbòbò, fún gbogbo ọkọ̀ àwọn oníṣòwò àwọn ọkọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ Ìgbéraga ènìyàn ni a ó tẹ̀ lórí ba a ó sì rẹ ìgbéraga ènìyàn sílẹ̀, Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà, gbogbo ère òrìṣà yóò pòórá Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpáta àti sínú ihò ilẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa àti ògo ọlá ńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò má a sọ àwọn ère fàdákà àti ère wúrà tí wọ́n ti yá fún bíbọ sí èkúté àti àwọn àdán, Wọn yóò ṣálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpáta àti sínú ihò pàlàpálá àpáta kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa àti ògo ọlá ńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́ èmí ẹni tó wà ní imú un rẹ̀ kín ni ó jámọ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Sí Éjíbítì Àti Kúṣì Ní ọdún tí ọ̀gágun, tí Ṣágónì ọba Ásíríà rán an, wá sí Ásídódù, ó kọ lùú ó sì kó o— ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa ti ẹnu Àìṣáyà ọmọ Ámósì jáde Ó sọ fún un pé, Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní araà rẹ kí o sì bọ́ ṣálúbàtà kúrò ní ẹṣẹ̀ rẹ Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòòhò àti láì wọ bàtà Lẹ́yìn náà ni Olúwa wí pé, Gẹ́gẹ́ bí Ìránṣẹ́ mi Àìsáyà ti lọ káàkiri ní ìhòòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àmì àti àpẹẹrẹ sí Éjíbítì àti Kúṣì, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Áṣíríà yóò kó àwọn ìgbèkùn Éjíbítì lọ ní ìhòòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kúṣì, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí goloto—bí àbùkù Éjíbítì Gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Kúṣì tí wọ́n sì ń fi Éjíbítì yangàn ni ẹ̀rù yóò dé bá tí a ó sì dójútì wọ́n Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní etí òkun yóò wí pé, Wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a ti gbọ́kànlé, àwọn tí a sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ láti ọwọ́ ọba Ásíríà! Báwo ni a ó ṣe sálà   Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Sí Bábílónì Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan ihà lẹ́bàá òkun Gẹ́gẹ́ bí ìjì líle ti í jà kọjá ní ilẹ̀ ní gúṣù, akógunjàlú kan wá láti ihà, láti ilẹ̀ ìpayà Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fi hàn mí ọlọ̀tẹ̀ ti tasírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù Élámù kojújà! Mẹ́díà ti tẹ̀gùn! Èmi yóò mú gbogbo Ìpayínkeke dópin, ni ó búra Pẹ̀lú èyí, ìrora kómi lára gírígírí, ìrora gbámimú, gẹ́gẹ́ bí i ti obìnrin tí ń rọbí, Mo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́, ọkàn mi pòrúúrù nípa ohun tí mo rí Ọkàn mí dàrú, ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi, tanmọóko tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ rí ti wá di ìpayà fún mi Wọ́n tẹ́ tábìlì, wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká, wọ́n jẹ, wọ́n mu! Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin òṣìṣẹ́, ẹ kún aṣà yín! Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi Lọ, kí o bojúwòde kí o sì jẹ́ kí ó wá sọ ohun tí ó rí Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin, àwọn agun-kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àwọn tí ó gun ràkúnmí, jẹ́ kí ó múra sílẹ̀, àní ìmúra gidigidi Báyìí ni alóre náà kígbe, Láti ọjọ́ dé ọjọ́, Olúwa mi, mo dúró ní ilé ìṣọ́, alaalẹ́ ni mo fi ń wà nípò mi Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀wá yìí nínú kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin Ó sì mú ìdáhùn padà wá Bábílónì ti ṣubú, ó ti ṣubú! Gbogbo àwọn ère òrìṣàa rẹ̀ ló fọ́nká lórí ilẹ̀! Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gúnmọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà, mo sọ ohun tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Dúmáhì Ẹnìkan ké sí mi láti Séírì wá Alóre, kí ló kù nínú òru náà Alóre náà dáhùn wí pé, Òwúrọ̀ súnmọ́tòsí, àti òru náà pẹ̀lú Bí ìwọ yóò bá béèrè, béèrè kí o sì tún dẹ̀yìn padà wá Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Arábíyà Ẹ̀yin ẹgbẹ́ èrò ti Dídánítì, tí ó pàgọ́ sínú igbó Arábíyà, gbé omi wá fún àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ ẹ̀yin tí ó ń gbé Tẹ́mà, gbé oúnjẹ wá fún àwọn ìsáǹsá Wọ́n sá kúrò lọ́wọ́ idà, kúrò lọ́wọ́ idà tí a fàyọ, kúrò lọ́wọ́ ọrun tí ó lò àti kúrò nínú ìgbóná ogun Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi Láàrin ọdún kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ọgbà, í ti í kà á, gbogbo ayẹkẹ Kédárì yóò wá sí òpin Àwọn tafàtafà tí ó ṣálà, àwọn jagunjagun Kédárì kò ní tó nǹkan Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ó ti sọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Jérúsálẹ́mù Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ àfonífojì ti ìran Kí ni ó ń dààmú un yín báyìí, tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ, Ìwọ ìlú tí ó kún fún dàrúdàpọ̀, Ìwọ ìlú rúkèrúdò òun rògbòdìyàn Àwọn tó ṣubú nínú un yín ni a kò fi idà pa, tàbí ojú ogun ni wọ́n kú sí Gbogbo àwọn olóríi yín ti jùmọ̀ sálọ a ti kó wọn nígbékùn láì lo ọrun ọfà Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀, lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀ta sì wà lọ́nà jínjìnréré Nítorí náà ni mo wí pé, Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi jẹ́ kí n ṣunkún kíkorò Má ṣe gbìyànjú àti tùmí nínú nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi Olúwa , Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan tí rúkèrúdò, rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ní àfonífojì ìmọ̀, ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀ àti síṣun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè Élámù mú àpò-ọfà lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin, kírí yọ apata rẹ̀ síta Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́-ogun, àwọn ẹlẹ́ṣin ni a sọdó sí ẹnu bodè ìlú gbogbo ààbò Júdà ni a ti ká kúrò Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náà sí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú ihà, Ìwọ rí i pé ìlúu Dáfídì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀, ìwọ ti tọ́jú omi sínú adágún ti ìsàlẹ̀ Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù ó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ìgànná lágbára Ìwọ mọ agbemi sí àárin ògiri méjì fún omi inú adágún àtijọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀ tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ó gbérò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ ṣẹ́yìn Olúwa , àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun, pè ọ́ ní ọjọ́ náà láti ṣunkún kí o sì pohùnréré, kí o tu irun rẹ dànù kí o sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora Ṣùgbọ́n Wòó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà màlúù pípa àti àgùntàn pípa, ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu! Jẹ́ kí a jẹ kí a mu, ni ẹ̀yin wí, Nítorí pé lọ́la àwa ó kú! Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mímọ̀ létíì mi Títí di ọjọ́ ikúu yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí, ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun Èyí ni ohun tí Olúwa , àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé, fún Ṣébínà, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ọ rẹ̀ Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín-yìí àti pé ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín-yìí, tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta Kíyèṣára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí kí ó sì jù ọ́ nù, Ìwọ ọkùnrin alágbára Òun yóò ká ọ rúgúdú bí i bọ́ọ̀lù yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀ èdè ńlá kan Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà— ìwọ ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ! Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ, a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ Ní ọjọ́ náà Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliákímù ọmọ Hílíkíyà Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́ n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́ Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jérúsálẹ́mù àti fún ilée Júdà Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilée Dáfídì lé e ní èjìká ohunkóhun tí ó bá sí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ẹnikẹ́ni kì yóò le è sí Èmi yóò sì kàn án mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní àyèe rẹ̀ òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀ Gbogbo ògo ìdílée rẹ̀ ni yóò rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ gbogbo ohun èlò aláìlágbára láti orí abọ́ rẹ̀ dé orí ìdẹ̀ rẹ̀ Ní ọjọ́ náà, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní àyèe rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lóríi rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀ Olúwa ni ó ti sọ ọ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Nípa Tírè Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Tírè Pohùnréré, ìwọ ọkọ̀-ojú omi Táṣíṣì! Nítorí a ti pa Tírè run láìsí ilé tàbí èbúté Láti ilẹ̀ Ṣáípúrọ́sì ni ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù àti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sídónì, ẹ̀yin tí àwọn awẹ̀kun ti sọ dọlọ́rọ̀ Láti orí àwọn omi ńlá ni irúgbìn oníhóró ti ilẹ̀ Ṣíhórì ti wá ìkóórè ti Náì ni owóòná Tírè, òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún àwọn orílẹ̀ èdè Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Ṣídónì àti ìwọ àní ìwọ ilé-ààbò ti òkun, nítorí òkun ti sọ̀rọ̀ Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí Èmi kò tí ì wọ àwọn ọmọkùnrin tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Éjíbítì, wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa ìròyìn láti Tírè Kọjá wá sí Táṣíṣì pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyáa yín, ògbólógbòò ìlú náà, èyí tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré Ta ló gbérò èyí sí Tírè, ìlú aládé, àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ aládé tí àwọn oníṣòwò o wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká ní orílẹ̀ ayé Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀, láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá ilé ayé sílẹ̀ Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò Náì, Ìwọ ọmọbìnrin Táṣíṣì, nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́ Olúwa ti na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde sí orí òkun ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Fonísíà pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run Ó wí pé, Kò sí àríyá fún ọ mọ́ ìwọ wúndíá ti Ṣídónì, tí a ti tẹ̀rẹ́ báyìí! Gbéra, rékọjá lọ sí Ṣáípúrọ́sì, níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì, àwọn ènìyàn tíkò jámọ́ nǹkankan bàyìí Àwọn Ásíríà ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ohun abẹ̀mí ihà wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gun wọn ṣókè, wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòòhò wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn Pohùnréré, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Táṣíṣì wọ́n ti pa odi rẹ̀ run! Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tírè fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tírè gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè Mú hápù kan, rìn kọjá láàrin ìlú, Ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé lu hápù rẹ dáadáa, kọ ọ̀pọ̀ orin, kí a lè ba à rántíi rẹ Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá Tírè jà Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ èree rẹ̀ àti owó iṣẹ́ẹ rẹ̀ ni a ó yà ṣọ́tọ̀ fún Olúwa a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́ Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú Olúwa , fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ Ìparun Kíyèsí i, Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayé yóò sì pa á run òun yóò pa ojúu rẹ̀ rẹ́ yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri— bákan náà ni yóò sì rí fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn, fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀, fún ìya-ilé àti ọmọbìnrin, fún olùtà àti olùrà, fún ayáni àti atọrọ fún ayánilówó àti onígbésè Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátapáta a ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì ṣá, ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un, àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́ wọ́n ti pa àwọn òfin run wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́ Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù, àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ, gbogbo àwọn alárìíyá sì kérora Àríyá ti tamborínì ti dákẹ́ ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúró ayọ̀ hápù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́ Kò ṣeéṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́ ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu Ìlú tí a run ti dahoro, ẹnu ọ̀nà à bá wọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì gbogbo ayọ̀ọ wọn ti di ìbànújẹ́, gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro, ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì ti pa bámú bámú Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé àti láàrin àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi ólífì, tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn tí a kórè èso tán Wọ́n gbé ohùn wọn ṣókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀ láti ìwọ̀ oòrùn ni wọn yóò ti polongo ọlá-ńlá Olúwa Nítorí náà ní ìlà oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa gbé orúkọ Olúwa ga, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní àwọn erékùṣù ti inú òkun, Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin Ògo ni fún olódodo n nì Ṣùgbọ́n mo wí pé, mo ṣègbé, mo ṣègbé! Ègbé ni fún mi! Alárékérekè dalẹ̀! Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀! Ìpáyà, isà-òkú, àti ìdẹkùn ń dúró dè ọ́, Ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayà yóò ṣubú sínú ihò, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihò ni ìdẹkùn yóò gbámú Ibodè ọ̀run ti wà ní sísí sílẹ̀ Ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì Ilẹ̀ ayé ti fọ́ ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù, a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí, ó bì síwá ṣẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́ Ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́ Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò jẹ ẹ́ níyà gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé A ó dà wọ́n papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n tí a dè nínú un túbú, a ó tì wọ́n mọ́ inú ẹ̀wọ̀n a ó sì jẹ wọ́n ní ìyà lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti òòrùn nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jọba ní orí òkè Ṣíhónì àti ní Jérúsálẹ́mù, àti níwájú àwọn alàgbà rẹ ní ògo Ẹ Yin Olúwa , ìwọ ni Ọlọ́run un mi Èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì fi ìyìn fún orúkọọ̀ rẹ nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́ o ti ṣe ohun ńlá, àwọn ohun tí o ti gbèròo rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́ Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà, ìlú olódi ti di ààtàn, ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́ a kì yóò tún un kọ́ mọ́ Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò bọ̀wọ̀ fún ọ àwọn ìlú orílẹ̀ èdè aláìláàánú yóò bọlá fún ọ Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòsì ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njúu rẹ̀ ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru Nítorí pé èémí àwọn ìkà dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní ihà O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì, gẹ́gẹ́ bí òjìji kùrukùru ṣe ń dín ooru kù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́ Ní ori òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ti pèṣè àṣè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn àpèjẹ ti wáìnì àtijọ́ ti ẹran tí ó dára jù àti ti wáìnì tí ó gbámúṣé Ní orí òkè yìí ni yóò parun aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn, abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀ èdè mọ́lẹ̀ Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé Olúwa gbogbo ayé yóò sì nu gbogbo omijé nù, kúrò ní ojúu gbogbo wọn Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn an rẹ̀ kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé Olúwa ni ó ti sọ ọ́ Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé, Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú un rẹ̀, òun sì gbà wá là Èyí ni Olúwa , àwa gbẹ́kẹ̀lé e, ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú un wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀ Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìí ṣùgbọ́n a ó tẹ Móábù mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀ Wọn yóò na ọwọ́ọ wọn jáde nínú un rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde láti lúwẹ̀ẹ́ Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ọwọ́ ọ wọn Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀ wọn yóò sì wà nílẹ̀ Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀, àní sí erùpẹ̀ lásán Orin Ìyìn Kan Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Júdà Àwa ní ìlú alágbára kan, Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe ògiri àti ààbò rẹ̀ Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn kí àwọn olódodo orílẹ̀ èdè kí ó lè wọlé, orílẹ̀ èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́ Ìwọ yóò paámọ́ ní àlàáfíà pípé ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin, nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé, nítorí Olúwa , Olúwa ni àpáta ayérayé náà Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀ ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀ ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹṣẹ ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀ Ẹṣẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ẹṣẹ̀ aninilára n nì, ipaṣẹ̀ àwọn òtòsì Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú Ìwọ adúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà àwọn olódodo kúnná Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa , rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ àwa dúró dè ọ́ orúkọọ rẹ àti òkìkíì rẹ àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́ Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ Nígbà tí ìdájọ́ọ̀ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkà wọn kò kọ́ láti ṣòdodo kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́n tẹ̀ṣíwájú láti máa ṣe ibi wọn kò sì ka ọlá ńlá Olúwa sí Olúwa , ti gbé ọwọ́ọ rẹ̀ sókè ṣùgbọ́n àwọn kò rí i Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ kí ojú kí ó tì wọ́n jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn ọ̀ta rẹ jó wọn run Olúwa , ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ ni ó ṣe é fún wa Olúwa Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìíràn lẹ́yìn rẹ ti jọba lé wa lórí, ṣùgbọ́n orúkọọ̀ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láàyè mọ́ gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́ Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán, Ìwọ pa gbogbo ìrántíi wọn rẹ́ pátapáta Ìwọ ti mú orílẹ̀ èdè gbòòrò, Olúwa ìwọ ti mú orílẹ̀ èdè bí sí i Ìwọ ti gba ògo fún araàrẹ ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ ṣẹ́yìn Olúwa , Wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njúu wọn nígbà tí o jẹwọ́n ní ìyà, wọ́n tilẹ̀ fẹ́ ẹ̀ má le gbàdúrà kẹ́lẹ́ kẹ́lẹ́ Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ bímọ tí í rúnra tí ó sì ń sunkún nínú ìrora rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájúu rẹ Olúwa Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé Ṣùgbọ́n àwọn òkúu yín yóò wà láàyè ara wọn yóò dìde Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀, dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀ Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀, ayé yóò bí àwọn òkúu rẹ̀ lọ́mọ Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wùu yín lọ kí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn in yín, ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀ títí tí ìbínú un rẹ̀ yóò fi rékọjá Kíyèsíì, Olúwa ń jáde bọ̀ láti ibùgbé e rẹ̀ láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí oríi rẹ̀, kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́ Ìdáǹdè Ísírẹ́lì Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò fi idà rẹ̀ jẹni níyà idà rẹ̀ amúbí-iná tí ó tóbi tí ó sì lágbára Lẹ́fíátanì ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì, Lẹ́fíátanì ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì Òun yóò sì pa ewèlè inú òkun náà Ní ọjọ́ náà Kọrin nípa ọgbà-àjàrà eléso kan ÈMI Olúwa ń bojú tó o, Mo ń bomirin ín láti ìgbàdégbà Mò ń sọ́ ọ tọ̀sán tòru kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára Inú ò bí mi Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí! Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun Èmi yóò sì dáná ṣun gbogbo wọn Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lúu mi, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lúu mi Ní ọjọ́ iwájú Jákọ́bù yóò ta gbòǹgbò, Ísírẹ́lì yóò tanná yóò sì rudi èṣo rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé Ǹjẹ́ Olúwa ti lù ú gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀ Ǹjẹ́ a ti pa á gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á Nípa ogun-jíjà àti lílé nílùú ni ó fi dojú kọ ọ́ pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà oorùn fẹ́ Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà fún ẹ̀ṣẹ̀ Jákọ́bù, èyí ni yóò sì jẹ́ èṣo kíkún ti ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, kì yóò sí ọ̀pá Áṣérà tàbí pẹpẹ tùràrí tí yóò wà ní ìdúró Ìlú olódi náà ti dahoro, ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀tì gẹ́gẹ́ bí aṣálẹ̀ níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹko níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀ wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ gbẹ, a kán wọn dànù àwọn obìnrin wá wọ́n, sì fi wọ́n dáná nítorí àwọn ènìyàn tí òye kò yé ni wọ́n jẹ́ Nítorí náà ni Ẹlẹ́dàá wọn kò ṣe yọ́nú sí wọn Ẹlẹ́dàá wọn kò sì síjú àánú wò wọ́n Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó ooré láti ìṣàn omi Éúfírétì wá títí dé Wádì ti Éjíbítì, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Ísírẹ́lì, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Ásíríà àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Éjíbítì yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù Ègbé Ni Fún Éfráímù Ègbé ni fún òdòdó-ẹ̀yẹ náà, tí í ṣe ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Éfáímù, àti sí òdòdó náà tí ń rọ, tí í ṣe ògo ẹwàa rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú àti sí ìlú náà ìgbéraga àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wáìnì! Kíyèsíì, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le tí ó sì lágbára, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wọ́ yìnyín àti bí àtẹ̀gùn apanirun, gẹ́gẹ́ bí àrọ̀ọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ẹ̀kún omi wá, òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀ Òdòdó-ẹ̀yẹ náà, tí í ṣe ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Éfáímù, òun ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀ Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú, yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkóórè bí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ọ rẹ̀, òun a sì mì ín Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ́ adé tí ó lógo, Òdòdó tí ó lẹ́wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́-òdodo fún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́-ìdájọ́ àti oríṣun agbára fún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnubodè Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀n ọ́n gbọ̀n ọ́n fún ọtí wáìnì wọ́n pòòrì dànìn fún ọtí bíà, Àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀n ọ́n gbọ̀n ọ́n fún ọtí bíà wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí bíà, wọ́n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran, wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá Gbogbo orí i tábìlì ni ó kún fún èébì kò sì sí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́ Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìhìn in rẹ̀ fún Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú un wọn, sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú Nítorí tí í ṣe Ṣe kí o ṣe, ṣe kí o ṣe, àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹ díẹ̀ níhìnín, díẹ̀ lọ́hùn ún Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀ Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí ṣọ̀rọ̀ àwọn tí ó sọ fún wí pé, Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi àti pé, èyí ni ibi ìsinmi ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tísílẹ̀ Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di pé ṣe kí o ṣe, ṣe kí o ṣe, àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹ díẹ̀ níhìnín, díẹ̀ ní ọ̀hún bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubu ṣẹ́yìn, wọn yóò farapa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa , ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, tí ń jọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jérúsálẹ́mù Ẹ fọ́n pé, Àwa ti bá ikú mulẹ̀, pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá, kò le kàn wá lára, nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa àti àìṣòtítọ́ ibi ipamọ́ wa Fún ìdí náà èyí ni ohun tí Olúwa Jèhófà sọ Kíyèsíì, mo gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Ṣíhónì òkúta tí a dánwò, òkúta igunlé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀le kì yóò ní ìfòyà Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òṣùwọ̀n àti òdòdó òjé òṣùwọ̀n yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́, omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí ẹ ń farapamọ́ sí mọ́lẹ̀ Májẹ̀muu yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fagi lé àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá, a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀ Nígbàkúùgbà tí ó bá ti wá ni yóò máa gbé ọ lọ, ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru, ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ Ìmòye ọ̀rọ̀ ìmọ̀ yìí yóò máa mú ìpayà ńlá wá Ibùsùn kúrújù fún ìnara lé lórí, ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká Olúwa yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní òkè Péráṣímù yóò ru ara rẹ̀ ṣókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní àfonífojì Gíbíónì— láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀, yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀ Ní ìsinsìn yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i Olúwa , àní Olúwa àwọn-ogun ti sọ fún mi nípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi, fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn yóò ha máa tulẹ̀ títí títí ni Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti tẹ́ ilẹ̀ pẹrẹṣẹ òun kì yóò ha gbìn káráwè kí ó sì fọ́n irúgbìn kúmínì ká bí Òun kì yóò ha gbin jéró sí àyè e tirẹ̀ ọkà báálì sì àyè e tirẹ̀, àti Ṣípẹ́lítì ní oko tirẹ̀ Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ sọ́nà ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tótọ́ A kì í fi òòlù pa káráwé tàbí kẹ̀kẹ́-ẹrù là á fi yí kúmínì mọ́lẹ̀ ọ̀pá ni a fi ń lu káráwé, àti kúmínì pẹ̀lú igi A gbọdọ̀ lọ hóró kí a tó ṣe àkàrà bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé Bí ó tilẹ̀ yí ẹṣẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lóríi rẹ̀, àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́ Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá, oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n Ègbé Ni Fún Ìlúu Dáfídì Ègbé ni fún ọ, Áríẹ́lì, Áríẹ́lì, ìlú níbi tí Dáfídì tẹ̀dó sí! Fi ọdún kún ọdún sì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀ṣíwájú Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ èmi yóò dó ti Áríẹ́lì òun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sunkún, òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo Èmi yóò sì fi ilé-ìṣọ́ yí ọ ká èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdótini mi dojú kọ ọ́ Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀ Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti iwin láti ilẹ̀ wá, láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹ yóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́ Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná, agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù Lójijì, ní ìṣẹ́jú àáyá, Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò wá pẹ̀lú àrá, ilẹ̀ ríri àti ariwo ńlá àti ẹ̀fúúfù líle àti iná ajónirun orílẹ̀ èdè tí ó bá Áríẹ́lì jà, tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódì rẹ̀ tí ó sì dó tì í, yóò dàbí ẹni pé nínú àlá, bí ìran ní òru Lẹ́yìn náà, ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun, ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lúu rẹ̀ àti bí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mumi, ṣùgbọ́n nígbà tí ó yajú pẹ́ ẹ́, pẹ̀lú òùngbẹ tí kò dáwọ́ dúró ni Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè tí ń bá òkè Ṣíhónì jà Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín, ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì, ẹ ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, ṣùgbọ́n kì í se ti ọtí bíà Olúwa ti mú oorun ìjìká wá sóríi yín ó ti dì yín lójú ó ti bo oríi yín Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, Jọ̀wọ́ ka èyí, òun yóò dáhùn pé, Èmi kò lè kà á a ti dì í ní èdìdì Tàbí bí ẹ bá fún ẹni tí kò lè ka ìwé kíká náà tí ẹ sì sọ pé, Jọ̀wọ́ ka èyí, òun yóò dáhùn pé, Èmi kò mọ̀ ọ́n kà Olúwa wí pé Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi Ìsìn wọn fún mi ni a gbé ka orí òfin tí àwọn ọkùnrin kọ́ ni Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé, ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa , tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn tí wọ́n sì rò pé, Ta ló rí wa Ta ni yóò mọ̀ Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀, bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀! Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé Òun kọ́ ló ṣe mí Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé, kò mọ nǹkan Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́ a kò ní sọ Lẹ́bánónì di pápá ẹlẹ́tù lójú àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí ihà Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà, láti inú fìrífìrí àti òkùnkùn ni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran Lẹ́ẹ̀kan síi àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì Aláìláàánú yóò pòórá, àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò dàwátì, gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀— àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi, ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní kóòtù tí ẹ fi ẹ̀rí èkè dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́ Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa , ẹni tí ó ra Ábúráhámù padà sọ sí ilé Jákọ́bù Ojú kì yóò ti Jákọ́bù mọ́ ojúu wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́ Nígbà tí wọ́n bá ríi láàrin àwọn ọmọ wọn, àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi, wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́, wọn yóò tẹ́wọ́gba mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jákọ́bù wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì Gbogbo àwọn tí ń rìn ṣégeṣège ní ẹ̀mí yóò jèrè ìmọ̀ gbogbo àwọn tí ń ṣe àròyé yóò gba ìtọ́sọ́nà Ìdájọ́ Lóríi Jérúsálẹ́mù Àti Júdà Kíyèsí i, Olúwa , Olúwa àwọn ọmọ-ogun, fẹ́ mú ìpèsè àti ìrànlọ́wọ́ kúrò ní Jérúsálẹ́mù àti Júdà gbogbo ìpèsè ounjẹ àti ìpèsè omi àwọn akíkanjú àti jagunjagun, adájọ́ àti wòlíì, aláfọ̀sẹ àti alàgbà, balógun àádọ́ta àti bọ̀rọ̀kìnní ènìyàn, olùdámọ̀ràn, oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́ àti ògbójú oníṣegùn Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn, ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sì máa jọba lóríi wọn Àwọn ènìyàn yóò sì má a pọ́n ọmọnìkejì wọn lójú ẹnìkan sí ẹnìkejìi rẹ̀, aládùúgbò sí aládùúgbò rẹ̀ Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbogun ti àwọn àgbà, àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí bọ̀rọ̀kìnní Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínu àwọn arákùnrin rẹ̀ mú nínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé, Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa, sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí! Ṣùgbọn ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé, Èmi kò ní àtúnṣe kan Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ò ní aṣọ nílé, ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà Jérúsálẹ́mù ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n Júdà ń ṣubú lọ, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí Olúwa , láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn, wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sódómù wọn ò fi pamọ́! Ègbé ni fún wọn! Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn, nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èṣo iṣẹ́ ẹ wọn Ẹ̀gbé ni fún aṣebi! Ìparun wà lóríi wọn A ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn Àwọn ọ̀dọ̀mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójú àwọn obìnrin ń jọba lé wọn lórí Áà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti sìyín lọ́nà, wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín Olúwa bọ sí ipo rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́ Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́ Olúwa dojú ẹjọ́ kọ àwọn alàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ Ẹyin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi, ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín Kín ni èro yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun Olúwa wí pé, Àwọn obìnrin Ṣíónì jẹ́ agbéraga, wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn, tí wọn ń fojú pe ọkùnrin, tí wọn ń sọ̀dí bí wọn ti ń yan lọ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjan wọnjan lọ́rùn ẹṣẹ̀ wọn Nítorí náà Olúwa yóò mú egbò wá sórí àwọn obìnrin Ṣíónì, Olúwa yóò sì pá wọn ní agbárí Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti ìgbàrí àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú, gbogbo gèlè ìwégbà ọrùn ẹ̀ṣẹ̀ àti àyà, àwọn ìgo tùràrí àti òògùn, òrùka ọwọ́ àti ti imú, àwọn àtàtà aṣọ, àwọ̀lékè, agbádá àti àpamọ́wọ́, Díńgí wọn, aṣọ funfun nigínnigín ìbòrí àti ìbòjú Dípò òórùn dídùn, òórún búbubú ni yóò wá, okùn ni yóò wà dípò àmùrè, orí pípá ni yóò dípò ìrun ti a ṣe ní ọ̀ṣọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ ni yóò dípò aṣọ ẹ̀yẹ ìjóná dípò ẹwà Àwọn ọkùnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú, àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lójú ogun Àwọn bodè Síònì yóò sunkún kíkorò, wọn ó ṣọ̀fọ̀, nítorí ó dahoro, yóò jókòó ní orí ilẹ̀ Ègbé ni fún orílẹ̀-èdè alágídí náà, ni Olúwa wí, Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi, tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi, tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n lọ sí Éjíbítì láì ṣe fún mi, tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Fáráò fún ààbò, sí òjìji, Éjíbítì fún ibi ìsádi Ṣùgbọ́n ààbò Fáráò yóò já sí ìtìjú fún un yín, òjìji Éjíbítì yóò mú àbùkù báa yín Bí wọ́n tilẹ̀ ní àwọn òṣìṣẹ́ ní Sóánì tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hánísì, gbogbo wọn ni a ó dójútì, nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn, tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá, bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní Gúúsù Láàrin ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú, ti kìnnìún àti abo kìnnìún ti pamọ́lẹ̀ àti ejò olóró, àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀ wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ohun ìní wọn ní orí iké àwọn ràkunmí, sí orílẹ̀ èdè aláìlérè, sí Éjíbítì tí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ kò wúlò rárá Nítorí náà mo pè é ní Ráhábù Aláìlẹ́sẹ̀ nǹkankan Lọ nísinsìn yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara pátakó fún wọn, tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká, pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀ kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn àti ẹlẹ́tanu ọmọ, àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí sí ìtọ́ni Olúwa Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé, Ẹ má ṣe rí ìran mọ́! àti fún àwọn wòlíì, Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́! Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa, ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀, ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọwá pẹ̀lú Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì! Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì wí Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, ẹ gbáralé ìnilára kí ẹ sì gbọ́kànlé ẹ̀tàn, ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì tí ó sì wó lójijì, àti ńi ìṣẹ́jú àáyá Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdì tí a fọ́ yánkanyànkan àti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀, fún mímú èédú kúrò nínú ààrò tàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára, Ẹni-Mímọ́ ti Ísírẹ́lì wí Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà, ní ìdákẹ́jẹ́ ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn Ẹ̀yin wí pé, bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá! Ẹ̀yin wí pé, Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ Nítorí náà àwọn tí ń lée yín yóò yára! Ẹgbẹ̀rún yóò sá nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn ún gbogbo yín lẹ ó ṣálọ, tí a ó fi yín sílẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí igi àṣíá ní orí òkè, gẹ́gẹ́ bí àṣíá lórí òkè Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ Olúwa sì fẹ́ síjú àánú wò ọ́ ó dìde láti ṣàánú fún ọ Nítorí Olúwa jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́ Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é! Ẹ̀yin ènìyàn Ṣíhónì, tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ìwọ kì yóò ṣunkún mọ́ Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò farasin mọ́ pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsi, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀ Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, Ẹ kúrò níbí! Òun yóò sì rọ òjò fún un yín sí àwọn irúgbìn tí ẹ gbìn sórí ilẹ̀, oúnjẹ tí yóò ti ilẹ̀ náà wá yóò ní ọ̀rá yóò sì pọ̀ Ní ọjọ́ náà ni àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóò máa jẹ koríko ní pápá oko tútù tí ó tẹ́jú Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi amúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀ Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀míi wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò ṣàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré Òṣùpá yóò sì tàn bí òòrùn, àti ìtànsán òòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí Olúwa yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn Kíyèsí i, orúkọ Olúwa ti òkèèrè wá pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kùrukùru èéfín tí ó nípọn ètè rẹ̀ kún fún ìbínú ahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun Èémíi rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára, tí ó rú sókè dé ọ̀run Ó jọ àwọn orílẹ̀ èdè nínú asẹ́ ìparun ó sì fi sí àgbọ̀n àwọn ènìyàn kókó kan tí ó ń sì wọ́n lọ́nà Ẹ̀yin ó sì kọrin gẹ́gẹ́ bí i ti alẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe àjọyọ̀ àpéjọ mímọ́, ọkàn yín yóò yọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ènìyàn gòkè lọ pẹ̀lúu fèrè sí orí òkè Olúwa , àní sí àpáta Ísírẹ́lì Olúwa yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀ yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀ pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun, pẹ̀lúu mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín Ohùn Olúwa yóò fọ́ Áṣíríà túútúú, pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀ Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí Olúwa bá gbé lé wọn pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀ yóò jẹ́ ti ìlù tamborínì àti ti hápù, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun pẹ̀lú ẹ̀sẹ́ láti apá rẹ̀ A ti tọ́jú Tófẹ́tì sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́, a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jìn tí ó sì fẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná èémí Olúwa , gẹ́gẹ́ bí ìsàn ṣúfúrù tí ń jó ṣe mú un gbiná Ègbé Ni Fún Àwọn Tí Ó Gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì Ègbé ni fún àwọn tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì fún ìrànwọ́, tí wọn gbẹ́kẹ̀lée eṣin tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn, ṣùgbọ́n ti wọn kò bojúwo Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì n nì, tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Olúwa Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọgbọ́n ó sì lè mú ìparun wá òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà, àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi Ṣùgbọ́n ènìyàn ṣáà ni àwọn ará Éjíbítì wọn kì í ṣe Ọlọ́run ẹran ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde, ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọṣẹ̀, ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké àní kìnnìún ńlá lórí ẹranànjẹ rẹ̀ bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojúu rẹ̀, ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá láti jagun lórí òkè Ṣíhónì àti lórí ibi gíga rẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò Jérúsálẹ́mù, Òun yóò dáàbò bò ó yóò sì tú u sílẹ̀ Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀ Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ẹ yín ti ṣe Ásíríà yóò ṣubú lọ́wọ́ idà kan tí kò ti ọwọ́ ènìyàn wá idà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá alààyè ni yóò pa wọ́n Wọn yóò sì sá níwájú idà náà àti àwọn ọmọkùnrin wọn ni a ó fún ní iṣẹ́ ipá ṣe Ibi gíga wọn ni yóò wó lulẹ̀ nítorí ìpayà nípa ìrísí agbára ogun wọn, àwọn ọ̀gágun wọn yóò wárìrì, ni Olúwa wí, ẹni tí iná rẹ̀ ń bẹ ní Ṣíhónì, ẹni tí ìléru rẹ̀ wà ní Jérúsálẹ́mù Ìjọba Òdodo Náà Wòó, ọba kan yóò jẹ nínú òdodo àwọn olórí yóò máa ṣàkóso ní ìdájọ́ Ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò dàbí ìdáàbòbò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì, gẹ́gẹ́ bí odò omi nínú aṣálẹ̀ àti òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ òrùngbẹ Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní pàdé mọ́, àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀ Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè, àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege A kò ní pe òmùgọ̀ ní bọ̀rọ̀kìnní mọ́ tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún mọ̀dàrú Nítorí òmùgọ̀ ṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́run ó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan Olúwa kalẹ̀ ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófo àti fún àwọn tí òrùngbẹ ń gbẹ ni ó mú omi kúrò Ìlànà àwọn aṣa jẹ ti ìkà, ó pète oríṣìí ìlànà ibi láti pa aláìní run pẹ̀lú irọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ òtòsì sì tọ̀nà Ṣùgbọ́n bọ̀rọ̀kìnní ènìyàn a máa pète ohun ńlá àti nípa èrò rere ni yóò dúró Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidi ẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀, ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ! Ní ó lé díẹ̀ ní ọdún kan ẹ̀yin tí ọkàn an yín balẹ̀ yóò wárìrì ìkóórè àjàrà kò ní múnádóko, bẹ́ẹ̀ ni ìkóórè èṣo kò ní sí Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùn bẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀! Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò, ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ẹ yín Ẹ lu ọmú un yín fún pápá ìgbádùn náà, fún àwọn àjàrà eléso àti fún ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi ilẹ̀ tí ó ti kún fún ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n— bẹ́ẹ̀ ni, kẹ́dùn fún gbogbo ilé ìtura àti fún ìlú àríyá yìí Ilé olódi ni a ó kọ̀ sílẹ̀, ìlù aláriwo ni a ó kọ̀tì ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ìdànù títí láéláé, ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápá oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn, títí a ó fi tú Ẹ̀mí sí wa lórí láti òkè wá, àti ti aṣálẹ̀ tí yóò dí pápá oko ọlọ́ràá àti tí pápá ọlọ́ràá yóò dàbí ẹgàn Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀ àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá Èṣo òdodo náà yóò sì jẹ́ àlàáfíà àbájáde òdodo yóò sì jẹ́ ìdákẹ́jẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé títí láé Àwọn ènìyàn mi yóò máa gbé ní àlàáfíà ní ibùgbé àlàáfíà, ní àwọn ilé ààbò, ní àwọn ibi ìsinmi tí kò ti sí ìdíwọ́ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé yìnyín ti tẹ́jú igbó pẹrẹṣẹ àti tí ojú ìlú ti tẹ́ pẹrẹṣẹ pátapáta, báwo ni ẹ ó ti jẹ́ alábùkún tó, nípa gbíngbin irúgbìn sí ipa odò gbogbo, àti nípa jíjẹ́ kí àwọn màlúù yín àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ láìsí ìdíwọ́ Ìpọ́njú Àti Ìrànlọ́wọ́ Ègbé ni fún ọ, ìwọ apanirun, ìwọ tí a kò tí ì pa ọ́ run! Ègbé ni fún ọ, ìwọ ọ̀dàlẹ̀, ìwọ tí a kò tí ì dà ọ́! Nígbà tí o bá dẹ́kun à ń panirun a ó pa ìwọ náà run, nígbà tí o bá dẹ́kun à ń dani, a ó da ìwọ náà Olúwa ṣàánú fún wa àwa ń ṣàfẹ́ríi rẹ Má a jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀ ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá, nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀ èdè fọ́nká Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀ èdè ni a kórè gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn bọ́ lù ú A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga Òun yóò kún Ṣíhónì pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréré ẹkún ní òpópónà àwọn ikọ̀ àlàáfíà ṣunkún kíkorò Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣátì, kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nà A ti ba àdéhùn jẹ́, a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí, a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù, ojú ti Lẹ́bánónì ó sì ṣá Ṣárónì sì dàbí aginjù, àti Báṣánì òun Kámẹ́lì rẹ àwọn èwe wọn Ní ìsinsìn yìí ni èmi yóò dìde, ni Olúwa wí Ní ìsinsìn yìí ni a ó gbé mi ga, ní ìsinsìn yìí ni a ó gbé mi sókè Ìwọ lóyún fùfùléèléè, o sì bí koríko èémí rẹ iná ni tí ó ń jó ọ run A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn Ìwọ tí ó wà lọ́nà jínjìn, gbọ́ ohun tí mo ti ṣe Ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi! Èrù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Ṣíhónì ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú ìjóná àìnípẹ̀kun Ẹni tí ó ń rìn lódodo tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́, tí ó kọ èrè tí ó tibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etíi rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn tí ó sì di ojúu rẹ̀ sí àtipète ibi ọkùnrin náà nìyìí tí yóò gbé ní ibi gíga, ẹni tí ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi A ó máa mú àkàrà rẹ̀ wá bẹ́ẹ̀ ni omi kì yóò wọ́n ọn Ojúu rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀ yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójú tó ilé-ìṣọ́ wà Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn wọ̀nyẹn mọ́, àwọn ènìyàn tí èdè wọn farasin, pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yéni Gbójú ṣókè sí Ṣíhónì, ìlú àjọ̀dún wa, ojú rẹ yóò rí Jérúsálẹ́mù, ibùgbé àlàáfíà nnì, àgọ́ tí a kò ní yí padà àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti jẹ́ Alágbára kan fún wa Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńlá ńlá àti odò kéékèèkéé Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lóríi wọn, ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn Nítorí Olúwa ni onídàájọ́ wa, Olúwa ni olófin wa, Olúwa òun ni ọba wa òun ni ẹni tí yóò gbà wá là Gbogbo okùn rẹ ni ó ti dẹ̀ Ìgbókùnró kò fìdímúlẹ̀, wọn kò taṣọ agbọ́kọ̀rìn, lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun ni a ó pín àní arọ pẹ̀lú yóò ru ìkógun lọ Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń gbé Ṣíhónì tí yóò wí pé, èmi ń sàìsàn, àti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ń gbé ibẹ̀ ni a ó fojúfòdá Ìdájọ́ Ọlọ́run Lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Kò Fẹ́ Ọlọ́run Súnmọ́ tòsí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti gbọ́, tẹ́tísílẹ̀ ẹyín ènìyàn jẹ́ kí ayé gbọ́, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti ohun gbogbo tí ó ti inú un rẹ̀ jáde Nítorí ibínú Olúwa ń bẹ lára gbogbo orílẹ̀-èdè, àti irunú un rẹ̀ lórí gbogbo ogun wọn o ti fi wọ́n fún pipa, Àwọn ti a pa nínú un wọn ni a ó sì jù ṣóde, òórùn wọn yóò ti inú òkúu wọn jáde, àwọn òkè-ńlá yóò sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́, a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i takàdá, gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀, bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà, àti bí i bíbọ́ èṣo lára igi ọ̀pọ̀tọ́ Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run, kíyèsì í, yóò ṣọ̀kalẹ̀ wá sórí Édómù, sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ Idà Olúwa kún fún ẹ̀jẹ̀ a mú un ṣanra fún ọ̀rá, àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-agùtàn àti ewurẹ, fún ọ̀rá iwe àgbò— nítorí Olúwa ni ìrúbọ kan ní Bósírà, àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Édómù Àti àwọn àgbáǹréré yóò ba wọn ṣọ̀kalẹ̀ wá, àti àwọn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù pẹ̀lú àwọn akọ màlúù, ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin, a ó si fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di Ọlọ́ràá Nítorí ọjọ́ ẹ̀san Olúwa ni, àti ọdún ìsanpadà, nítorí ọ̀ràn Ṣíhónì Odò rẹ̀ ni a ó sì sọ di ọ̀dà, àti eruku rẹ̀ di imí-ọjọ́, ilẹ̀ rẹ̀ yóò sì di ọ̀dà tí ń jóná A ki yóò paá ní òru tàbí ní ọ̀sán, èéfín rẹ̀ yóò gòkè láéláé yóò dahoro láti ìran dé ìran, kò sí ẹnìkan tí yóò là á kọjá láé àti láéláé Ṣùgbọ́n ẹyẹ àṣá, àti àkàlà ni yóò ni ín, àti òun yóò sì na okùn-ìwọ̀n ìparun sóríi rẹ̀, àti òkúta ohun rudurùdu sórí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ Ní ti àwọn ìjòyè rẹ̀ ẹnìkan kì yóò sí níbẹ̀ ti wọn ó pè wá sí ìjọba, gbogbo àwọn olóríi rẹ̀ yóò sì di asán Ẹ̀gún yóò sì hù jáde nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí, ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀ Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá àti àgbàlá fún àwọn òwìwí Àwọn ẹran ijù àti àwọn ọ̀wàwà ni yóò pàdé, àti sátírè kan yóò máa kọ sí èkejìí rẹ̀, iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú, yóò sì rí ibi isinmi fún ara rẹ̀ Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ ṣíbẹ̀, yóò yé, yóò sì pa, yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀ àwọn gúnnugún yóò péjọ ṣibẹ̀ pẹ̀lú, olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀ Ẹ wá a nínú ìwé Olúwa , ẹ sì kà á Ọ̀kan nínú wọ̀nyí kì yóò yẹ̀, kò sí ọ̀kan tí yóò fẹ́ ìkejìi rẹ̀ kù nítorí Olúwa ti pàṣẹ ẹnu rẹ̀ ló sì fi kó wọn jọ Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì fi tò wọ́n jọ Ó ti di ìbò fún wọn, ọwọ́ rẹ̀ sì ti pín in fún wọn nípa títa okùn, wọn ó jogún rẹ̀ láéláé, láti ìran dé ìran ni wọn ó máa gbé inú un rẹ̀ Ayọ̀ Àwọn Ẹni Ìràpadà Aṣálẹ̀ àti ìyàngbẹ ilẹ̀ ni inú rẹ̀ yóò dùn ihà yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná Gẹ́gẹ́ bí ewéko kúrókúsì, òun yóò bẹ́ná jáde yóò yọ ayọ̀ ńlá ńlá yóò sì kígbe fún ayọ̀ Ògo Lẹ́bánónì ni a ó fi fún un, ọlá ńlá Kámẹ́lì àti Ṣárónì wọn yóò rí ògo Olúwa , àti ọlá ńlá Ọlọ́run wa Fún ọwọ́ àìlera lókun, mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù Ọlọ́run yín yóò wá, òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀ṣan pẹ̀lú ìgbẹ̀ṣan mímọ́ òun yóò wá láti gbà yín là Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́ Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀ Odò yóò tú jáde nínú ihà àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀ Yanrìn tí ń jóná yóò di adágún ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi Òpópó ibi tí àwọn ajáko sùn tẹ́lẹ̀rí koríko àti koríko odò àti ewéko mìíràn yóò hù níbẹ̀ Àti opópónà kan yóò wà níbẹ̀ a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà-Mímọ́ Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀, tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lóríi rẹ̀ a kì yóò rí wọn níbẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀, àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá Wọn yóò wọ Ṣíhónì wá pẹ̀lú orin ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn, ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn Ṣenakérúbù Dẹ́rùba Jérúsálẹ́mù Ní ọdún kẹrìnlá ìjọba Heṣekáyà, Ṣenakérúbù ọba Áṣíríà kọlu gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Júdà ó sì kó gbogbo wọn Lẹ́yìn náà, ọba Áṣíríà rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun láti Lákíṣì sí ọba Hẹṣikáyà ní Jérúsálẹ́mù Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúsàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá Alágbàfọ̀, Eliákímù ọmọ Hílíkáyà alábojútó ààfin, Ṣébínà akọ̀wé, àti Jóà ọmọ Áṣáfù akọ̀wé jáde lọ pàdé rẹ̀ Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, Ẹ sọ fún Heṣekáyà,  Èyí yìí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Áṣíríà sọ pé Lóríi kí ni ìwọ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé tìrẹ yìí lé Ìwọ sọ wí pé ìwọ ní ète àti agbára ogun—ṣùgbọ́n ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ aṣán Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tí ìwọ fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi Wò ó nísinsìn yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì ẹ̀rúnrún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sìí dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni Fáráò ọba Éjíbítì sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e Bí o bá sì sọ fún mi pé, Àwa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa, kì í ṣe òun ni Heṣekáyà ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Júdà àti Jérúsálẹ́mù pé, Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájúu pẹpẹ yìí  Ẹ wá nísinsìn yìí, bá ọ̀gá mi pàmọ̀ pọ̀, ọba Ásíríà Èmi yóò fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí! Báwo ni ẹ ṣe lè lé ẹyọ kanṣoṣo padà nínú èyí tí ó kéré jù nínú àwọn ìjòyè ọ̀gá mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì fún kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin Síwájú sí i, ǹjẹ́ mo wa lè wá bá ilẹ̀ yìí jà kí n sì pa á run láìsí Olúwa Olúwa fún rara rẹ̀ ló sọ pé kí n bá orílẹ̀ èdè yìí jà kí n sì paárun   Lẹ́yìn náà ni Eliákímù, Ṣébínà àti Jóà sọ fún ọ̀gágun náà pé, Jọ̀wọ́ máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Árámáíkì, nítorí pé àwa gbọ́ ọ Má ṣe bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri mọ́ Ṣùgbọ́n ọ̀gágun náà dá wọn lóhùn pé, Ṣé ẹ rò wí pé ọ̀gá yín àti ẹ̀yin nìkan ni ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ni, tí kì í sì ṣe sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí ó jókòó lórí ògiri, àwọn tí ó jẹ́ pé wọn yóò jẹ ìgbẹ́ wọn tí wọ́n yóò sì mu ìtọ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun náà dìde tí ó sì ké sítà ní èdè Hébérù pé, Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásíríà! Ohun tí ọba wí nìyìí Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà tàn yín jẹ Òun kò le è gbà yín sílẹ̀! Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbà tí ó sọ pé, Olúwa yóò kúkú gbà wá a kì yóò fi ìlú lé ọba Ásíríà lọ́wọ́ Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Heṣekáyà Ohun tí ọba Áṣíríà wí nìyìí Ẹ ṣètò àlàáfíà pẹ̀lúù mi kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá Lẹ́yìn náà ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mumi nínú kàǹga rẹ̀, títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i ti yín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn oníhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà sì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, Olúwa yóò gbà wá Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀ èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Áṣíríà bí Níbo ni àwọn òrìṣà Hámátì àti Ápádì ha wà Níbo ni àwọn òrìṣà Ṣépáfírámù ha wà Ǹjẹ́ wọn ti já Ṣamáríà gbà kúrò lọ́wọ́ mi bí Èwo nínú àwọn òrìṣà orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ló ha ti dáàbò bo ilẹ̀ẹ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi Báwo ni Olúwa ṣe wá le gba Jérúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà dákẹ́ rọ́rọ́ wọn kò sì mú èsì kankan wá, nítorí ọba ti pàṣẹ fún wọn pé, Ẹ má ṣe dá a lóhùn Lẹ́yìn náà ni Eliákímù ọmọ Híkílíà alákóṣo ààfin, Ṣébínà akọ̀wé àti Jóà ọmọ Áṣáfù akọ̀wé àkọsílẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Heṣekáyà pẹ̀lú aṣọ wọn ní fífàya, wọ́n sì sọ ohun tí ọ̀gágun ti wí A Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìdáǹdè Jérúsálẹ́mù Nígbà tí ọba Heṣekáyà gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara rẹ̀, ó sì wọ inú tẹ́ḿpìlì Olúwa lọ Òun sì rán Eliákímù alákoṣo ààfin, Ṣébínà akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì Wọ́n sọ fún un pé, Báyìí ni Heṣekáyà sọ ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ìtìjú gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ọmọdé kùdẹ̀dẹ̀ ìbí tí kò sì sí agbára láti bí wọn Ó lè jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Ásíríà ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́ Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láàyè Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Heṣekáyà dé ọ̀dọ̀ Àìṣáyà, Àìṣáyà sọ fún wọn pé, Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, Ohun tí Olúwa sọ nìyìí Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Ásíríà tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀ òdì sí mi Tẹ́tísílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀ èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà   Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Áṣíríà ti fi Lákísì sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Líbínà jà Ní àkókò yìí Ṣenakérúbù gbọ́ ìròyìn kan pé Tíhákà ará Kúṣì ọba Éjíbítì ń jáde bọ̀ wá bá òun jà Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Heṣekáyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí Ẹ sọ fún Heṣekáyà ọba Júdà pé Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, a kì yóò jọ̀wọ́ Jérúsálẹ́mù fún ọba Ásíríà Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Ásíríà ti ṣe sí àwọn orílẹ̀ èdè, tí ó pa wọ́n run pátapáta Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gósénì, Háránì, Résípì àti àwọn ènìyàn Ẹ́dẹ́nì tí wọ́n wà ní ìlú Áṣárì Níbo ni ọba Hámátì wà, ọba Ápádì, ọba Ìlú Ṣefáfíámù tàbí Hénà tàbí Ífà Heṣekáyà gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ó sì kà á Lẹ́yìn náà ni ó gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì Olúwa ó sì tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú Olúwa Heṣekáyà sì gbàdúrà sí Olúwa Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó gúnwà láàrin àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lóríi gbogbo ìjọba orílẹ̀ ayé Ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé Tẹ́tí sílẹ̀, Ìwọ Olúwa , kí o gbọ́, ya ojú rẹ, Ìwọ Olúwa , kí o rí i tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ṣenakérúbù rán láti fi àbùkù kan Ọlọ́run alààyè Òtítọ́ ni ìwọ Olúwa pé àwọn ọba Ásíríà ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán Wọ́n ti da àwọn òrìṣà wọn sínú iná wọ́n sì ti pa wọ́n run, nítorí àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run bí kò ṣe igi àti òkúta lásán, tí a ti ọwọ́ ènìyàn ṣe Nísinsìn yìí, Ìwọ Olúwa , Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ọ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, Olúwa ni Ọlọ́run Lẹ́yìn náà Àìṣáyà ọmọ Ámósì rán iṣẹ́ kan sí Heṣekáyà Èyí ni ohun tí Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ pé Nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Ṣenakérúbù ọba Áṣíríà, èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀ Wúndíá ọmọbìnrin Ṣíhónì kẹ́gàn ó sì fi ọ ṣe yẹ̀yẹ́ Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù mi oríi rẹ̀ bí ó ti ń sálọ Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀ òdì sí Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè tí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga Sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì! Nípa àwọn oníṣẹ́ rẹ ìwọ ti mú àbùkù bá Olúwa Ìwọ sì ti sọ wí pé pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin mi Èmi ti gun orí òkè ńlá ńlá, ibi gíga jùlọ ti Lébánónì Èmi ti gé igi kédárì rẹ tí ó ga jùlọ lulẹ̀, àti àyànfẹ́ igi páínì Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ, igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ Èmi ti gbẹ́ kàǹga ní ilẹ̀ àjèjì mo sì mu omi ní ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ́lẹṣẹ̀ mi Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Éjíbítì Ṣé o kò tí ì gbọ́ Tipẹ́ tipẹ́ ni mo ti fìdíi rẹ̀ mulẹ̀ Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀ ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ, pé o ti sọ àwọn ìlú olódi di àkójọpọ̀ àwọn òkúta Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù, ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhù tuntun, gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé, tí ó jóná kí ó tó dàgbà ṣókè Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wà àti ìgbà tí o wá tí o sì lọ àti bí inú rẹ ṣe ru sími Nítorí pé inú rẹ ru sími àti nítorí pé oríkunkun rẹ ti dé etíìgbọ́ mi, Èmi yóò fi ìwọ mi sí ọ ní imú, àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu, èmi yóò sì jẹ́ kí o padà láti ọ̀nà tí o gbà wá Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ Ìwọ Heṣekáyà Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnraà rẹ̀, àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara ìyẹn Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè, ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èṣo wọn Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́ku láti ilé Júdà yóò ta gbòǹgbò níṣàlẹ̀ yóò sì ṣo èṣo lókè Nítorí láti Jérúsálẹ́mù ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá, àti láti òkè Ṣíhónì ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọba Ásíríà Òun kì yóò wọ ìlú yìí wá tàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ín Òun kì yóò wá síwájúu rẹ pẹ̀lú asà tàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un Nípa ọ̀nà tí ó gbàwá náà ni yóò padà lọ òun kì yóò wọ inú ìlú yìí, ni Olúwa wí Èmi yóò dáàbò bo ìlú yìí èmi ó sì gbàá là, nítorí mi àti nítoríì Dáfídì ìránṣẹ́ mi! Lẹ́yìn náà ni ańgẹ́lì Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní i ibùdó àwọn Ásíríà Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú! Nítorí náà Ṣenakérúbù ọba Ásíríà fọ́ bùdó ó sì pẹṣẹ̀dà Òun sì padà sí Nínéfè, ó sì dúró síbẹ̀ Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń jọ́sìn nínú tẹ́ḿpìlì Níṣírókì òrìṣà rẹ, àwọn ọmọ rẹ̀ Adiramélékì àti Ṣáréṣà gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Árárátì Bẹ́ẹ̀ ni Ẹsahadoni ọmọ rẹ̀ sì gba ipo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Àìṣàn Heṣekáyà Ní ọjọ́ náà ni Heṣekáyà ṣe àìṣàn dé ojú ikú Wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, Ohun tí Olúwa wí nìyìí palẹ̀ iléẹ̀ rẹ mọ́, bí ó ti yẹ nítorí pé ìwọ yóò kú ìwọ kì yóò dìde àìṣàn yìí Heṣekáyà yí ojúu rẹ̀ sí ara ògiri, ó sì gba àdúrà sí Olúwa , Rántí, Ìwọ Olúwa , bí mo ti rìn pẹ̀lú òtítọ́ níwájúù rẹ, àti bí mo ti fi ọkàn dídúró ṣinṣin ṣe ohun tí ó dára ní ojúù rẹ Bẹ́ẹ̀ ni Heṣekáyà sì ṣunkún kíkorò Lẹ́yìn náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Àìṣáyà wá pé Lọ kí o sì sọ fún Heṣekáyà pé, Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ọlọ́run Dáfídì baba rẹ sọ pé Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀dógún kún ọjọ́ ayé rẹ Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Áṣíríà Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí  Èyí yìí ni àmì tí Olúwa fún ọ láti fi hàn wí pé Olúwa yóò mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ Èmi yóò mú òjìji òòrùn kí ó padà ṣẹ́yìn ní ìsísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi ṣọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Áhásì   Bẹ́ẹ̀ ni òòrùn padà ṣẹ́yìn ní ìsíṣẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀ Ìwé tí Heṣekáyà ọba Júdà kọ lẹ́yìn àìṣàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán Èmi wí pé, Ní àárin gbùngbùn ọjọ́ ayé mi èmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikú kí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù Èmi wí pé, Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́, àni Olúwa , ní ilẹ̀ àwọn alààyè èmi kì yóò lè síjú wo ọmọnìyàn mọ́, tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ń gbe orílẹ̀ ayé báyìí Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mi ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ọ̀ mi Gẹ́gẹ́ bí ahunsọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà ọ̀ṣán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi Èmi fi ṣùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́jú, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi ọ̀ṣán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi Èmi sunkún gẹ́gẹ́ bí ìṣáré tàbí ìgún, Èmi pohùnréré gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run Ìdààmú bámi Ìwọ Olúwa , wá fún ìrànlọ́wọ́ mi! Ṣùgbọ́n kí ni èmi lè sọ Òun ti bá mi ṣọ̀rọ̀ àti pé òun tìkálára rẹ̀ ló ti ṣe èyí Èmi yóò máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mi nítorí ìpọ́njú ẹ̀mí mi yìí Olúwa , nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú un wọn pẹ̀lú Ìwọ dá ìlera mi padà kí o sì jẹ́ kí n wà láàyè Nítòótọ́ fún àǹfààní mi ni pé mo jẹ ìyà irú ìpọ́njú báyìí Nínú ìfẹ́ rẹ ni o pamí mọ́ kúrò nínú ọ̀gbun ìparun ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ Nítorí pé iṣà òkú kò le è yìn ọ́, ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ Olúwa yóò gbà mí là bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókun ní gbogbo ọjọ́ ayé wa nínú tẹ́ḿpìlì ti Olúwa Àìṣáyà ti sọ pé, Pèṣè ìsù kí o sì fi sí ojú oówo náà, òun yóò sì gbádùn Heṣekáyà ti sọ pé, Kí ni yóò jẹ́ àmì pé èmi yóò gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì Olúwa Àwọn Ikọ̀ Ọba Láti Bábílónì Ní àkókò náà ni Méródákì-Báládánì ọmọ Báládánì ọba Bábílónì fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Heṣekáyà, nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn Heṣekáyà gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀ tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìpanǹkan mọ́ hàn wọn—sílífà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Heṣekáyà kò fi hàn wọ́n Lẹ́yìn náà wòlíì Àìṣáyà lọ sí ọ̀dọ̀ Heṣekáyà ọba ó sì béèrè pé, Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá Láti ilẹ̀ jínjìnnà, ni èsì Heṣekáyà Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti Bábílónì Wòlíì náà sì béèrè pé, Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi ni ìdáhùn Heṣekáyà Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fi hàn wọ́n Lẹ́yìn náà ni Àìṣáyà sọ fún Heṣekáyà pé, Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kó jọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkólọ sí Bábílónì Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni Olúwa wí Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwọ̀fà nínú ààfin ọba Bábílónì Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ dára, ni èsì Heṣekáyà Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, Àlàáfíà àti ààbò yóò wà ní Ìgbà ayé tèmi Ẹ̀ka Ní ọjọ́ náà, obìnrin méje yóò dì mọ́ ọkunrin kan yóò sì wí pé, Àwa ó má a jẹ oúnjẹ ara wa a ó sì pèsè aṣọ ara wa sáà jẹ́ kí a má a fi orúkọ rẹ̀ pè wá Mú ẹgan wá kúrò! Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ogo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Ísírẹ́lì Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Síhónì, àwọn tí o kù ní Jérúsálẹ́mù, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jérúsálẹ́mù Olúwa yóò wẹ ẹgbin àwọn obinrin Síhónì kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí ìná Lẹ́yìn náà, Olúwa yóò dá sorí òkè Síhónì àti sóríi gbogbo àwọn tí ó péjọ pọ̀ ṣíbẹ̀, kúrúkúrú èéfín ní ọ̀ṣán àti ìtànsán ọ̀wọ́ iná ní òru, lórí gbogbo ògo yìí ni ààbò yóò wà Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò Ìtùnnú Fún Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run Ẹ tùú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú, ni Ọlọ́run yín wí Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jérúsálẹ́mù kí o sì kéde fún un pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí, pé à ti san gbésè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ Ohùn ẹnìkan tí ń pè Nínú ihà ẹ pèṣè ọ̀nà sílẹ̀ fún Olúwa ṣe é kí ó tọ́ ní ihà òpópónà fún Ọlọ́run wa Gbogbo àfonífojì ni a ó gbé ṣókè, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti ọ̀nà pálapàla ni a yóò sọ di títẹ́jú pẹrẹṣẹ, Ògo Olúwa yóò sì di mímọ̀ gbogbo ọmọnìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rii Nítorí ẹnu Olúwa ni ó ti sọ ọ́ Ohùn kan wí pé, Kígbe ṣókè Èmi sì sọ pé, Igbe kí ni èmi ó ké Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko, àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná inú un pápá Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Ṣíhónì, lọ sí orí òkè gíga Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jérúsálẹ́mù, gbé ohùn rẹ ṣókè pẹ̀lú ariwo, gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù sọ fún àwọn ìlúu Júdà, Ọlọ́run rẹ nìyìí! Wò ó, Olúwa àwọn ọmọ-ogun náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára, apá rẹ̀ sì ń jọba fún un Wò ó, ère rẹ̀ sì wà pẹ̀lúu rẹ̀, àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀ Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan-àyàa rẹ̀ ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ da rí àwọn tí ó ní ọ̀dọ́ Ta ni ó ti wọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀, tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀ tí ó wọn àwọn ọ̀run Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀-ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀, tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n àti òkè kéékèèkéé nínú òṣùwọ̀n Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa , tàbí tí ó ti tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀ Ta ni Olúwa ké sí kí ó là á lọ́yẹ àti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́ Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́n tàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀ èdè dàbí i ẹ̀kán-omi nínú garawa a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n Lẹ́bánónì kò tó fún pẹpẹ iná, tàbí kí àwọn ẹranko rẹ̀ kí ó tó fún ẹbọ sísun Níwájúù rẹ ni gbogbo orílẹ̀ èdè dàbí ohun tí kò sí gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò tí kò tó ohun tí kò sí Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀ Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á, ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ó tí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un Ọkùnrin kan tí ó talákà ju kí ó lè mú irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá, wá igi tí kò le è rà Ó wá oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́ láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀ ìwọ kò tí ì gbọ́ A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpilẹ̀ ayé Òun jókòó lórí Ìtẹ́ ní òkè òbììrí ilẹ̀ ayé, àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà, ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé Ó sọ àwọn ọmọ ọba di aṣán àti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n, kété tí a gbìn wọ́n, kété tí wọ́n tita ẹ̀kan nínú ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ, bẹ́ ni ìji-líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò Ta ni ẹ ó fi mi wé Tàbí ta ni ó bámi dọ́gba ni Ẹni-Mímọ́ wí Gbé ojú rẹ ṣókè kí o sì wo àwọn ọ̀run Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan tí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀, ọ̀kanṣoṣo nínú wọn kò sọnù Èéṣe tí o fi sọ, Ìwọ Jákọ́bù àti tí o ṣàròyé, Ìwọ Ísírẹ́lì Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi Ìwọ kò tí ì mọ̀ Ìwọ kò tí ì gbọ́ Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé, Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀-ayé Òun kì yóò ṣàárẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì, àti ìmọ̀ rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdiwọ̀n rẹ̀ Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀ ó sì fi kún agbára àwọn aláàárẹ̀ Àní àwọn ọ̀dọ́ ń rẹ̀wẹ̀sì, ó ń rẹ̀ wọ́n, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò tún agbára wọn ṣe Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì wọn yóò ṣáré àárẹ̀ kò ní mú wọn, wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn Olùrànlọ́wọ́ Fún Ísírẹ́lì Ẹ dákẹ́ jẹ́ ẹ́ níwájúù mi ẹ̀yin erékùṣù! Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè tún agbára wọn ṣe! Jẹ́ kí wọn wá ṣíwájú kí wọn sọ̀rọ̀ Jẹ́ kí a pàdé pọ̀ ní ibi ìdájọ́ Ta ni ó ti ru ẹnìkan ṣókè láti ìlà-oòrùn wá, tí ó pè é ní òdodo sí iṣẹ́ tirẹ̀ Ó gbé àwọn orílẹ̀ èdè lé e lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun àwọn ọba níwájúu rẹ̀ Ó sọ wọ́n di erùpẹ̀ pẹ̀lú idà rẹ̀, láti kù ú níyàngbò pẹ̀lú ọrun rẹ̀ Ó ń lé pa wọn ó sì tẹ̀ṣíwájú láì farapa, ní ojú ọ̀nà tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ kò rìn rí Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé, tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe Èmi Olúwa pẹ̀lú ẹnì kìn-ín-ní wọn àti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi ni ẹni náà Àwọn erékùsù ti rí i wọ́n bẹ̀rù ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé wárìrì Wọ́n súnmọ́tòsí wọ́n sì wá síwájú Èkínní ran èkejì lọ́wọ́ ó sì sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé Jẹ́ alágbára! Oníṣọ̀nà gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú, àti ẹni tí ó fi òòlù dán an mú òun lọ́kàn le, àní ẹni tí ó ń lu owú Ó sọ nípa àjópọ̀ náà pé, Ó dára Ó kan ère náà mọ́lẹ̀ kí ó má ba à wó lulẹ̀ Ṣùgbọ́n ìwọ, Ìwọ Ísírẹ́lì, ìránṣẹ́ mi, Jákọ́bù, ẹni tí mo ti yàn, ẹ̀yin ìran Ábúráhámù, ọ̀rẹ́ mi, mo mú ọ láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé, láti kọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó jìnnà jùlọ ni mo ti pè ọ́ Èmi wí pé, Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi Èmi ti yàn ọ́ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì tí ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lúù rẹ má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́ Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹni yẹ̀yẹ́ gbogbo àwọn tí ó lòdì sí ọ yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀ta rẹ, ìwọ kì yóò rí wọn Gbogbo àwọn tí ó gbógun tì ọ́ yóò dàbí òfuuru gbádá Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ Ìwọ má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù kòkòrò, Ìwọ Ísírẹ́lì kékeré, nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́, ni Olúwa wí, olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà, tuntun tí ó mú ti eyín rẹ̀ mu, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá, ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú, a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú, àti ẹ̀fúùfù yóò sì gbá wọn dànù Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú Olúwa ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì Àwọn talákà àti aláìní wá omi, ṣùgbọ́n kò sí ahọ́n wọn ṣáàápá fún òrùngbẹ Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò dá wọn lóhùn Èmi, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní àwọn ibi gíga pọ́nyán ún, àti oríṣun omi ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi, àti ilẹ̀ tí ó ṣáàápá yóò di orísun omi Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀ igi kédárì àti akaṣíà, mítílì àti ólífì Èmi yóò da páínì sí inú ilẹ̀ síṣá, igi fíri àti ṣípírẹ́ṣì papọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀, kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn, pé ọwọ́ Olúwa ni ó ti ṣe èyí, àti pé Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ni ó ti dá èyí Mú ẹjọ́ wá, ni Olúwa wí Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀, ni ọba Jákọ́bù wí Mú àwọn ère-òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún wa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́, kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọn kí àwa sì mọ àbájáde wọn níparí Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá, ẹ sọ fún wa ohun ti ọjọ́ iwájú mú dání kí àwa kí ó lè mọ̀ pé Ọlọ́run niyín Ẹ ṣe nǹkankan, ìbáà ṣe rere tàbí búburú, tó bẹ́ẹ̀ tí àyà yóò fi fò wá tí ẹ̀rù yóò sì fi kún inú wa Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ko já sí nǹkankan iṣẹ́ yín ni kò sì wúlò fún ohunkóhun ẹni tí ó yàn yín jẹ́ ẹni ìríra Èmi ti ru ẹnìkan sókè láti àríwá, òun sì ń bọ ẹnìkan láti ìlà oòrùn tí ó pe orúkọ mi Òun gun àwọn aláṣẹ mọ́lẹ̀ bí ẹni pé odò ni wọ́n, àfi bí ẹni pé amọ̀kòkò nì ti ń gún amọ̀ Ta ni ó sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, tí àwa kò bá fi mọ̀, tàbí ṣáájú àkókò, tí àwa kò bá fi wí pé, Òun sọ òtítọ́ Ẹnikẹ́ni kò sọ nípa èyí, ẹnikẹ́ni kò sàṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó sọ fún Ṣíhóńì pé, Wò ó, àwọn nìyìí! Mo fún Jérúsálẹ́mù ní ìránṣẹ́ ìhìn ayọ̀ kan Èmi wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan— kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó lè mú ìmọ̀ràn wá, kò sí ẹnìkan tí ó lè dáhùn nígbà tí mo bi wọ́n Kíyèsí i, irọ́ ni gbogbo wọn! Gbogbo ìṣe wọn já sí asán àwọn ère wọn kò ṣé kò yà fún afẹ́fẹ́ àti dàrúdàpọ̀ Ìránṣẹ́ Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀ Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀ òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀ èdè Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe ṣókè, tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ ṣókè ní òpópónà Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́ àti òwú-àtùpà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá Òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì títí tí yóò fi fi ìdájọ́ mulẹ̀ ní ayé Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètíi wọn sí Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n ṣóde, tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú un wọn, Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú un rẹ̀ Èmi, Olúwa , ti pè ọ́ ní òdodo Èmi yóò di ọwọ́ọ̀ rẹ mú Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà láti la àwọn ojú tí ó fọ́, láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn Èmi ni Olúwa orúkọ mi nìyìí! Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmìíràn tàbí ìyìn mi fún ère-òrìṣà Kíyèsí i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé, àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé kí wọn tó hù jáde mo ti kéde rẹ̀ fún ọ Kọ orin titun sí Olúwa ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá, ẹ̀yin tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú un wọn Jẹ́ kí ihà àti àwọn ìlúu rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn ṣókè jẹ́ kí ibùdó ti àwọn igi kédárì ń gbé máa yọ̀ Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Ṣẹ́là kọrin fún ayọ̀ jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwa àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù Olúwa yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára, gẹ́gẹ́ bí jagunjagun yóò ti gbé ohun ipá rẹ̀ ṣókè pẹ̀lú ariwo, òun yóò ké igbe ogun òun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀ta rẹ̀ Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí, mo ṣunkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahoro tí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣù n ó sì gbẹ àwọn adágún Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀, ní ipa-ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájúu wọn àti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà, tí wọ́n wí fún ère pé, Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa, ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú Gbọ́, ìwọ adití, wòó, ìwọ afọ́jú, o sì rí! Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi, àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí, ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Olúwa Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkankan Ó dùn mọ́ Olúwa nítorí òdodo rẹ̀ láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan níyìí tí a jà lógun tí a sì kó lẹ́rú, gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun, tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n Wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀ wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹni tí yóò sọ pé, Dá wọn padà Ta ni nínú un yín tí yóò tẹ́tí sí èyí tàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀ Ta ni ó fi Jákọ́bù lélẹ̀ fún ìkógun, àti Ísírẹ́lì sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí Kì í há ṣe Olúwa ni, ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀ wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí, rògbòdìyàn ogun Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀ èdè kò yé wọn ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá Olùgbàlà Ísírẹ́lì Kanṣoṣo Ṣùgbọ́n ní ìsinsìn yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, Ìwọ Jákọ́bù ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ tèmi ni ìwọ ṣe Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá, Èmi yóò wà pẹ̀lúu rẹ àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀ Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá, kò ní jó ọ ahọ́n iná kò ní jó ọ lára Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì Olùgbàlà rẹ Èmi fi Éjíbítì ṣe ìràpadà rẹ, Kúṣì àti Ṣébà dípò rẹ Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi, àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ, Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ, àti ènìyàn dípò ẹ̀míì rẹ Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lúù rẹ Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà oòrùn wá èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀ oòrùn Èmi yóò sọ fún àríwá pé, Fi wọ́n sílẹ̀! àti fún gúṣù, Má ṣe dá wọn dúró Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jínjìn wá àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé— ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́, tí mo dá fún ògo mi, tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde, tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití Gbogbo orílẹ̀ èdè kóra wọn jọ àwọn ènìyàn sì kóra wọn papọ̀ Ta ni nínú wọn tó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ yìí tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá láti fi hàn pé wọ́n tọ̀nà tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tí wọn yóò sọ pé, Òtítọ́ ni Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, ni Olúwa wí, Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà ḿi gbọ́ tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá, tàbí a ó wa rí òmìíràn lẹ́yìn mi Èmi, àní Èmi, Èmi ni Olúwa , yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrin yín Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, ni Olúwa wí, Pé Èmi ni Ọlọ́run Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà Èyí ni ohun tí Olúwa wí olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Bábílónì láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá, gbogbo ará Bábílónì nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga Èmi ni Olúwa , Ẹni Mímọ́ rẹ, Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì, ọba rẹ Èyí ni ohun tí Olúwa wí Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú òkun, ipa-ọ̀nà láàrin alagbalúgbú omi, ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde, àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀, wọ́n sì ṣùn ṣíbẹ̀, láìní lè dìde mọ́, wọ́n kú pirá bí òwú fìtílà Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́ Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun! Nísinsìn yìí ó ti yọ ṣókè àbí o kò rí i bí Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi, àwọn ajáko àti àwọn òwìwí, nítorí pé mo pèṣè omi nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá, láti fi ohun-mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi, àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí, Ìwọ Jákọ́bù, àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítoríì mi Ìwọ Ísírẹ́lì Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ ọrẹ sísan, tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ oníhóró tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí Ìwọ kò tí ì ra kálámọ́ọ́sì olóòórùn dídùn fún mi, tàbí kí o da ọ̀rá-ẹbọ rẹ bò mí Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedédé yín Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ àwọn àìṣedédé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi, tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́ Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi, jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀ ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀ àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi Nítorí náà, èmi yóò dójú ti àwọn ẹni àyẹ́sí inú tẹ́ḿpìlìi yín, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò mú ìparun bá Jákọ́bù àti ìtìjú bá Ísírẹ́lì Ísírẹ́lì Tí A Yàn Ṣùgbọ́n tẹ́tísílẹ̀ nísinsìn yìí, Ìwọ Jákọ́bù, Ìránṣẹ́ mi Ísírẹ́lì, ẹni tí mo ti yàn Ohun tí Olúwa wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́ láti inú ìyá rẹ wá, àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú Má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù, ìránṣẹ́ mi, Jéṣúrúnì ẹni tí mo ti yàn Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ àti àwọn odò ni ilẹ̀ gbígbẹ Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ, àti ìbùkún mi sóri àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ Wọn yóò dàgbà ṣókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù, àti gẹ́gẹ́ bí igi póǹpóla léti odò tí ń sàn Ọ̀kan yóò wí pé, Èmi jẹ́ ti Olúwa òmìíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jákọ́bù bẹ́ẹ̀ ni òmìíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, Ti Olúwa , yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Ísírẹ́lì Ohun tí Olúwa wí nìyìí ọba Ísírẹ́lì àti Olùdáǹdè, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn, lẹ́yin mi kò sí Ọlọ́run kan Ta ni ó dàbí ì mi Jẹ́ kí o kéde rẹ̀ Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi Kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀, àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀ bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ aṣọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ típẹ́típẹ́ Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ha ń bẹ lẹ́yìn mi Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn Èmi kò mọ ọ̀kankan Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán, àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́ kò jámọ́ nǹkankan Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú wọ́n jẹ́ aláìmọ́kan sí ìtìjú ara wọn Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère, tí kò lè mú èrè kankan wá fún un Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójú tì àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì fi ìdúró wọn hàn gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú Ìpayà àti àbùkù Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò, ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú ó fi òòlù ya ère kan, ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀, Ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ̀n ọ́n ó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe àmì sí ara rẹ̀, Ó tún fi ṣísẹ́lì họ ọ́ jáde ó tún fi kọ́ḿpáásì ṣe àmì sí i Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀, kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà Ó gé igi kédárì lulẹ̀, tàbí bóyá ó mú Ṣípírẹ́sì tàbí óákù Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrin àwọn igi inú igbó, ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́, ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín ó yá ère, ó sì ń forí balẹ̀ fún un Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná lóríi rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀, ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé, Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀ ó forí balẹ̀ fún un, ó sì sìn ín Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé, Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi Wọn kò mọ nǹkankan, nǹkankan kò yé wọn a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkankan bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkankan Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú, kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye láti sọ wí pé, Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná Mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀, Mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́ Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ̀tàn ni ó sì í lọ́nà òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́ Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, Ìwọ Jákọ́bù nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, Ìwọ Ísírẹ́lì Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe, Èmi Ísírẹ́lì, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kùrukùru, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀ Padà sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ padà Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí Olúwa ló ti ṣe èyí kígbe ṣókè, Ìwọ ilẹ̀ ayé níṣàlẹ̀ Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá, ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín, nítorí Olúwa ti ra Jákọ́bù padà, ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Ísírẹ́lì Ohun tí Olúwa wí nìyìí Olùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́ láti inú ìyá rẹ wá Èmi ni Olúwa tí ó ti ṣe ohun gbogbo tí òun nìkan ti na àwọn ọ̀run tí o sì tẹ́ ayé pẹrẹṣẹ òun tìkálára rẹ̀, ta ni ó ba àmì àwọn wòlíì èké jẹ́ tí ó sì sọ àwọn tí ń woṣẹ́ fún ni di òmùgọ̀, tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọgbọ́n délẹ̀ tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀, ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde tí ó sì mú àṣọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ, ẹni tí ó wí nípa ti Jérúsálẹ́mù pé, a ó máa gbénú un rẹ̀, àti ní ti àwọn ìlú Júdà, A ó tún un kọ́, àti àwọn ahoro rẹ̀, Èmi yóò mú un bọ̀sípò, ta ni ó sọ fún omi jínjìn pé, Ìwọ gbẹ, èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ, ta ni ó sọ nípa Ṣáírọ́ọ́ṣì pé, Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́ òun yóò sọ nípa Jérúsálẹ́mù pé, Jẹ́ kí a tún un kọ́, àti nípa tẹ́ḿpìlì, Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀   Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀, sí Kírúsì, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú láti dojú àwọn orílẹ̀ èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀ àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn, láti sí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà Èmi yóò lọ ṣíwájú rẹ èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹṣẹ Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ èmi ó sì gé ọ̀pá irin Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn, ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó farasin, Tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Èmi ni Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ Nítorí Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi àti Ísírẹ́lì ẹni tí mo yàn Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ, mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí Èmi ni Olúwa , àti pé kò sí ẹlòmìíràn yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan, Èmi yóò fún ọ ní okun, bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí, tí o fi jẹ́ pé láti ìlà oòrùn títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀ kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn mo mú àlàáfíà wá, mo sì dá àjálù Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀ jẹ́ kí àwọ̀sánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀ Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbàgàdà, jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè, jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ Èmi Olúwa ni ó ti dá a Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà, ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrin àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀ Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé Kí ni ohun tí ò ń ṣe Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé, Òun kò ní ọwọ́ Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé Kí ni o bí tàbí sí ìyá rẹ̀, Kí ni ìwọ ti bí Ohun tí Olúwa wí nìyìí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀ Nípa ohun tí ó ń bọ̀, ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi, tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé tí ó sì da ọmọnìyàn sóríi rẹ̀ Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run mo sì kó àwọn agbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta Èmi yóò gbé Kírúsì ṣókè nínú òdodo mi Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́ Òun yóò tún ìlú mi kọ́ yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ohun tí Olúwa wí nìyìí Àwọn èròjà ilẹ̀ Éjíbítì àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kúṣì, àti àwọn Ṣábíáṣì— wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn, wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́ Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀, wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé, Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì sí ẹlòmìíràn kò sí ọlọ́run mìíràn   Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́, Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Ísírẹ́lì Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì wọn yóò sì kan àbùkù gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀ Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ni a ó gbàlà láti ọwọ́ Olúwa Pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójú tì yín, títí ayé àìnípẹ̀kun Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí— ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, Òun ni Ọlọ́run ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé, Òun ló ṣe é Òun kò dá a láti wà lófo, ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀— Òun wí pé Èmi ni Olúwa , kò sì sí ẹlòmìíràn Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó farasin, láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jákọ́bù pé Ẹ wá mi lórí asán Èmi Olúwa sọ òtítọ́ Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìṣáǹṣá láti àwọn ọrílẹ̀ èdè wá Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri, tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni J ẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀ Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́, ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe Kì í ha á ṣe Èmi, Olúwa Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi, Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà kò sí ẹlòmìíràn àfi èmi Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là, ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀-ayé nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì sí ẹlòmìíràn Nípa èmi tìkálára mi ni mo ti búra, ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lúu gbogbo ipá mi ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́ Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀ nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra Wọn yóò sọ ní ti èmi, Nínú Olúwa nìkan ni òdodo àti agbára wà   Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójú tì wọn Ṣùgbọ́n nínú Olúwa gbogbo àwọn ìran Ísírẹ́lì ni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga Àwọn Ọlọ́run Bábílónì Bẹ́lì tẹríi rẹ̀ ba, Nébò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti di àjàgà sí wọn lọ́rùn, ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀ wọn kò lè gba ẹrù náà, àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn Tẹ́tí sími ìwọ ilé Jákọ́bù, Gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Ísírẹ́lì, Ìwọ tí mo ti gbérò láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún, tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú oríi yín Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀ Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi tí àwa yóò jọ farawéra Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn wọ́n sì wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà, wọn sì tẹríba láti sìn ín Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n, wọ́n sì gbé e sí àye rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀ Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ, fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀ Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́tijọ́ Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlọ̀mìíràn Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmìíràn bí ì mi Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá Mo wí pé Ète mi yóò dúró, àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò múṣẹ èyí tí mo ti gbérò, òun ni èmi yóò ṣe Tẹ́tí sí mi, ìwọ ọlọ́kàn-dídi, ìwọ tí ó jìnnà sí òdodo Èmi ń mú òdodo mi bọ̀ nítòsí, kò tilẹ̀ jìnnà rárá àti ìgbàlà mi ni a kì yóò dádúró Èmi yóò fún Ṣíhónì ní ìgbàlà ògo mi fún Ísírẹ́lì Ìṣubú Bábílónì Ṣọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku, wúndíá ọmọbìnrin Bábílónì jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀ láìsí ìtẹ́, ọmọbìnrin àwọn ará Bábílónì A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́ Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun mú ìbòjú ù rẹ kúrò Ká yẹ̀rì rẹ sókè, kí o hó ẹṣẹ̀ rẹ sílẹ̀, kí o sì la inú odò lọ Ìhòòhò rẹ ni a ó fihàn síta àti ìtìjú rẹ ni a ó sí sílẹ̀ Èmi yóò sì gba ẹ̀ṣan Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ òun ni Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì Jókòó ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn, ọmọbìnrin àwọn ará Bábílónì a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrin àwọn ilẹ̀-ọba mọ́ Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mi tí mo sì ba ogún mi jẹ́ Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lú ní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé Ìwọ wí pé, Èmi yóò tẹ̀ṣíwájú títí láé— ọba-bìnrin ayérayé! Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsí nǹkan wọ̀nyí tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ Nísinsìn yìí, tẹ́tísílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé, Èmi ni, kò sì sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi Èmi kì yóò di opó tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ Méjèèjì yìí ni yóò wá sóríì rẹ láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà pípàdánù ọmọ àti dídi opó Wọn yóò wá sóríì rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ àti àwọn èpè rẹ tí kì í ṣélẹ̀ Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ ó sì ti wí pé, kò sí ẹni tí ó rí mi Ọgbọ́n àti òye rẹ ti sì ọ́ lọ́nà nígbà tí o wí fún ara rẹ pé, Èmi ni, kò sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi Ìparun yóò dé bá ọ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́ tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò òfò kan tí o kò le ròtì ni yóò wá lójijì sí oríì rẹ Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹ àti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo, tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá Bóyá o le è ṣàṣeyọrí, bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀ Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀! Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú, Àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ láti oṣù dé oṣù, jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ Lóòótọ́ wọ́n dàbí pòpó iná ni yóò jó wọn dànù Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là lọ́wọ́ agbára iná náà Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná níhìnín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìí gbogbo èyí ní o tí síṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀ tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀ kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́ Ísírẹ́lì Olóríkunkun Tẹ́tí sí èyí, Ìwọ ilée Jákọ́bù, ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Ísírẹ́lì tí o sì wá láti ẹ̀ka Júdà, ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ Olúwa tí o sì ń pe Ọlọ́run Ísírẹ́lì ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo Ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nì tí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Ísírẹ́lì— Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Èmi sọ àṣọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́, ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mímọ̀ Lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbéṣẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó àwọn iṣan ọrùn un yín irin ni wọ́n iwájúu yín idẹ ni Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọ ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́ kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé, Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́ sí i Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí wo gbogbo wọn Ǹjẹ́ o kò ní gbà wọ́n bí Láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi yóò máa sọ fún ọ nípa nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tí ó farasin tí ìwọ kò mọ̀ A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́ ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé, Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bí láti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró nítorí ìyìn ara mi, mo fà á ṣẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ, kí a má ba à ké ọ kúrò Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bí i fàdákà Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́ Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmìíràn Tẹ́tí sí mi, Ìwọ Jákọ́bù Ísírẹ́lì ẹni tí mo pè Èmi ni ẹni náà Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀, àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn dìde ṣókè papọ̀ Ẹ gbárajọ pọ̀ gbogbo yín kí ẹ sì dẹtí Èwo nínú àwọn ère òrìṣà rẹ ló ti sọ nǹkan wọ̀nyí Àkójọpọ̀ àwọn àyànfẹ́ Olúwa ni yóò gbé ète yìí jáde sí Bábílónì apá rẹ̀ ni yóò dojú kọ àwọn aráa Bábílónì Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é Èmi yóò mú un wá, òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀ Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀ ní àṣìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀ Àti ní àkókò yìí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó ti rán mi, pẹ̀lú ẹ̀mii rẹ̀ Èyí ni ohun tí Olúwa wí Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ, tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tísílẹ̀ sí àṣẹ mi, àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò, àti òdodo rẹ bí ìgbì òkun Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí i yanrìn, àwọn ọmọ yín bí i horo ọkà tí a kò lè kà tán orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi Fi Bábílónì sílẹ̀, sá fún àwọn ará Bábílónì, ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀ kí o sì kéde rẹ̀ Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé wí pé, Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jákọ́bù nídè Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn kọjá nínú ihà ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta ó fọ́ àpáta omi sì tú jáde Kò sí àlàáfíà, ni Olúwa wí, Fún àwọn ìkà Ìránṣẹ́ Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀ èdè jínjìn-nà réré kí a tó bí mi Olúwa ti pè mí láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n, ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pamí mọ́ ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán, ó sì fi mí pamọ́ sínú àpó rẹ̀ Ó sọ fún mi pé, Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe, Ísírẹ́lì nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn Ṣùgbọ́n èmi ṣọ pé, Mo ti ṣe wàhálà lórí asán mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀ mófo Síbẹ̀ síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sími sì wà lọ́wọ́ Olúwa , èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi Nísinsìn yìí Olúwa wí pé ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ láti mú Jákọ́bù padà tọ̀ mí wá àti láti kó Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú Olúwa Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi Òun wí pé Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi láti mú ẹ̀yà Jákọ́bù padà bọ̀ sípò àti láti mú àwọn ti Ísírẹ́lì tí mo ti pamọ́ Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà, kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá sí òpin ilẹ̀ ayé Ohun tí Olúwa wí nìyìí Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì— sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kóríra lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀ èdè, sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè, àwọn ọmọ ọba yóò ríi wọn yóò sì wólẹ̀, nítorí Olúwa ẹni tí í ṣe olótìítọ́, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tí ó ti yàn ọ́ Ohun tí Olúwa wí nìyìí Ní àkókò ojú rere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro, Láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, Ẹ jáde wá àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, Ẹ gba òmìnira! Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òrùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí òòrùn kí ó pa wọ́n Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn, tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi oríṣun omi Èmi yóò sọ gbogbo àwọn oke-ńlá mi di ojú-ọ̀nà àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé ṣókè Kíyèsí i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jínjìn àwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀ láti ìwọ̀ oòrùn, àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Áṣíwánì Ẹ hó fún ayọ̀, Ẹ̀yin ọ̀run yọ̀, ìwọ ilẹ̀-ayé bú sórin, ẹ̀yin òkè-ńlá! Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni tí a ń pọ́n lójú Ṣùgbọ́n Ṣíhónì sọ pé, Olúwa ti kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa ti gbàgbé è mi Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé Èmi kì yóò gbàgbé rẹ! Kíyèsí i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà, àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ Gbójú rẹ ṣókè kí o sì wò yíká gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọ wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ Níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè, ni Olúwa wí, Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́ ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahoro tí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìgbòrò, ní ìsinsìn yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ti ó jẹ ó rùn ni yóò wà ni ọ̀nà jínjìn réré Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹ yóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ, Ibi yìí ti kéré jù fún wa ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé, ta ló bí àwọn yìí fún mi Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn A sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀ Ta ló wo àwọn yìí dàgbà A fi èmi nìkan sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá   Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí níyìí Kíyèsí i, Èmi yóò késí àwọn aláìkọlà Èmi yóò gbé àṣíá mi ṣókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn Wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọn wọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ní èjìká wọn Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́-baba fún ọ, àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́ Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀ wọn yóò máa lá èrùpẹ̀ lẹ́bàá ẹṣẹ̀ rẹ Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mi ni a kì yóò jákulẹ̀ Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun, tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú Ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa wí níyìí Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbékùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun, àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú Ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà, àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹ ẹran ara wọn wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó bí ẹnii mu wáìnì Nígbà náà ni gbogbo ọmọnìyàn yóò mọ̀ pé Èmi, Olúwa , èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kanṣoṣo ti Jákọ́bù Orin Ọgbà-Àjàrà Náà Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn orin kan nípa ọgbà-àjàrà rẹ̀ Olùfẹ́ẹ̀ mi ní ọgbà-àjàrà kan ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà síi Ó kọ́ ilé-ìṣọ́ sí inú un rẹ̀ ó sì ṣe ìfúntí kan ṣíbẹ̀ pẹ̀lú Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára, ṣùgbọn èṣo búburú ni ó ti ibẹ̀ wá Ní ìsinsin yìí ẹ̀yín olùgbé Jérúsálẹ́mù àti ẹ̀yin ènìyàn Júdà ẹ ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àti ọgbà àjàrà mi Kín ni ó kù tí n ò bá tún ṣe sí ọgbà àjàrà mi Ju èyí tí mo ti ṣe lọ Nígbà tí mo ń wá èso dáradára, èéṣe tí ó fi ṣo kíkan Ní ìsinsìn yìí, èmi yóò sọ fún ọ ohun tí n ó ṣe sí ọgbà-àjàrà mi Èmi yóò gé igi inú un rẹ̀ kúrò, a ó sì pa á run, Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀ yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro láì kọ ọ́ láì rò ó, ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀ Èmi yóò sì pàṣẹ fún kùrukùru láti má ṣe rọ̀jò sóríi rẹ̀ Ọgbà-àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ilé Ísírẹ́lì àwọn ọkùnrin Júdà sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀ Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọn, ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni ó rí, Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ ẹkún ìpayínkeke Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sími létí Ó dájú pé àwọn ilé ńlá ńlá yóò di ahoro, àwọn ilé dára dára yóò wà láìní olùgbé Ọgbà-àjàrà sarè oko mẹwàá yóò mú ìkòkò wáìnì kan wá, nígbà tí òṣùwọ̀n hómérì kan yóò mú agbọ̀n irúgbin kan wá Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti lépa ọtí líle, tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́ títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì Wọ́n ní hápù àti láà níbi àṣè wọn, tamborínìn òun fèrè àti wáìnì, ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, kò sí ìbọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò lọ sí ìgbèkùn nítorí òye kò sí fún wọn, ebi ni yóò pa àwọn bọ̀rọ̀kìnní wọn kú ẹgbàágbèje wọn ni òrùgbẹ yóò sì gbẹ Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi, ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada, nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀ àti ọmọnìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀ ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀ Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀, Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀ Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn, àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀ Ègbé ni fún àwọn tí ń fi okùn, àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fí okùn kẹ́kẹ́ ẹ̀sìn fa ìkà, sí àwọn tí ó sọ pé, Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá, jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè ríi, jẹ́ kí ó súnmọ́ bí jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì kí ó dé, kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi, tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkunkun, tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn tí wọ́n já fáfá lójú ara wọn Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí, tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́ Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àkékù koríko run àti bí koríko ṣe relẹ̀ wẹ̀sì nínú iná, bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀ wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ ṣókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀ Àwọn òkè mì tìtì, àwọn òkú sì dàbí ààtàn lójú òpópó ọ̀nà Pẹ̀lúu gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíí kúrò, ọ̀wọ́ rẹ̀ sì gbé ṣókè síbẹ̀ Ó gbé ọ̀págun ṣókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà-réré, Ó súfèé sí àwọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀ Àwọn rè é, wọ́n ti sáré Kò rẹ ẹnìkankan nínú wọn, tàbí kí ó kọṣẹ̀ Ẹnikẹ́ni ò tòògbé tàbí sùn Ìgbànú ẹnìkankan ò dẹ̀ ní ìbàdí i rẹ̀, okùn sálúbàtà kan ò já Àwọn ọfà wọn múná, gbogbo ọrun wọn sì lò pátakò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta-akọ àwọn àgbá kẹ̀kẹ̀ wọn sì dàbí ìjì líle Bíbú wọn dàbí tí kìnnìhún, wọ́n bú bí ẹgbọ̀rọ̀ kìnnìhún, wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹranànjẹ wọn mú tí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórí gẹ́gẹ́ bí i rírú omi òkun Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀, yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́ pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kùrukùru rẹ̀ Ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì Àti Ìgbọ́ràn Ìráńṣẹ́ Ohun tí Olúwa wí níyìí Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà èyí tí mo fi lé e lọ Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi ni mo tà ọ́ fún Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́ nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́ Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun, Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀ àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi wọ́n sì kú fún òùngbẹ Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀ mo sì fi aṣọ-ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán, láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró O jí mi láràárọ̀, o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sí mi ní etí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí Èmi kò sì padà ṣẹ́yìn Mo sí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí, àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irúngbọ̀n mi Èmi kò fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọsùtì sí Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ràn mí lọ́wọ́ A kì yóò dójú tìmí Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí Òkúta akọ èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí Ẹni tí ó dámiláre wà nítòsí Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀ṣùn kàn mí Jẹ́ kí a kojú ara wa! Ta ni olùfisùn mi Jẹ́ kí ó kòmí lójú! Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó ń ràn mí lọ́wọ́ Ta ni ẹni náà tí yóò dámí lẹ́bi Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ kòkòrò ni yóò sì mú wọn jẹ Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa tí ó sì ń gbọ́ràn sí ìràńṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn tí kò ní ìmọ́lẹ̀, kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀ Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná tí ẹ sì ń pèṣè iná ìléwọ́ fún ara yín, ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín àti ti ìtùfú tí ẹ ti kánná lù Ohun tí ẹ ó gbà lọ́wọ́ mi nìyìí Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìpọ́njú Ìgbàlà Ayérayé Fún Ṣíhónì Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde ẹ wo Ábúráhámù baba yín, àti Ṣérà, ẹni tó bí i yín Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni, Èmi sì bùkún un, mo sì sọ́ọ́ di ọ̀pọ̀lọpọ̀ Dájúdájú, Olúwa yóò tu Ṣíhónì nínú yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀ Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Ídẹ́nì, gbogbo ìgbòrò rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa Ayọ̀ àti inúdídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ Tẹ́tí sími, ẹ̀yin ènìyàn mi gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀ èdè mi Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀ èdè Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan, ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà, àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá sí àwọn orílẹ̀ èdè Àwọn erékùṣù yóò wò mí wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run, wo ilẹ̀ ní ìṣàlẹ̀ ilẹ̀ Àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín, ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé, òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun tótọ́, ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyàa yín Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ Ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí Ẹ̀gbọ̀n òwú Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé, àti ìgbàlà mi láti ìrandíran Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára Ìwọ apá Olúwa dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì, àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́ Ìwọ kọ́ lo ké Rékábù sí wẹ́wẹ́ tí o sì fa ewèlè yẹn ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi òkun bí àti àwọn omi inú ọ̀gbun, Tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìṣàlẹ̀ òkun tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá Wọn yóò wọ Ṣíhónì wá pẹ̀lú orin kíkọ ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo oríi wọn Ayọ̀ àti inú-dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran-ara, àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán, tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ, ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀, tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́ nítorí ìbínú àwọn aninilára, tí wọ́n sì gbọ́kàn lé ipanirun Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ wọn kò ní kú sínú túbú wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ń ru òkun ṣókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́ Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí àyè rẹ̀, ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, àti ẹni tí ó sọ fún Ṣhíónì pé, Ẹ̀yin ni ènìyàn mi   Jí, jí! Gbéra nílẹ̀ Ìwọ Jérúsálẹ́mù, ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ Olúwa kọ́ọ̀bù ìbínú rẹ̀, ìwọ tí o ti fà á mu dégẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ fèrè tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀ngbọ̀nọ́n Nínú gbogbo ọmọ tí ó bí kò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ sọ́nà nínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́ kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́ Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ— ta ni yóò tù ọ́ nínú Ìparun àti Ìdahoro, ìyàn àti idà ta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà, gẹ́gẹ́ bí ẹtu tí a dé mọ́nú àwọ̀n Ìbínú Olúwa ti kún inú un wọn fọ́fọ́ọ́fọ́ àti ìbáwí Ọlọ́run yín Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́, tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì Ohun tí Olúwa yín Alágbára jùlọ wí nìyìí, Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn an rẹ̀ mọ́ Kíyèsí i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ọ̀ rẹ kọ́ọ̀bù tí ó mú ọ ta gbọ̀ngbọ̀nọ́n láti inú kọ́ọ̀bù náà, ẹ̀kan ìbínú mi, ni ìwọ kì yóò mu mọ́ Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nnílójú rẹ lọ́wọ́, àwọn tí ó wí fún ọ pé, Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lóríì rẹ Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lóríi rẹ̀ Ìpọ́njú àti Ògo Ìránṣẹ́ Náà Jí, jí, Ìwọ Ṣíhónì, wọ ara rẹ ní agbára Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀, Ìwọ Jérúsálẹ́mù, ìlú mímọ́ n nì Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́ kì yóò wọ inú un rẹ mọ́ Gbọn eruku rẹ kúrò dìde ṣókè, kí o sì gúnwà, Ìwọ Jérúsálẹ́mù Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò, Ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbékùn Ṣíhónì Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́, láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì láti gbé láìpẹ́ ni Áṣíríà pọ́n wọn lójú Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí ni Olúwa wí Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn tí ó sì ń jọba lé wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, ni Olúwa wí Àti ní ọjọọjọ́ orúkọ mi ni a ṣọ̀rọ̀ òdì sí nígbà gbogbo Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni ó ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè ẹṣẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìn rere ayọ̀ wá, tí wọ́n kéde àlàáfíà, tí ó mú ìyìn rere wá, tí ó kéde ìgbàlà, tí ó sọ fún Ṣíhónì pé, Ọlọ́run rẹ ń jọba! Tẹ́tísílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn ṣókè wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀ Nígbà tí Olúwa padà sí Ṣíhónì, wọn yóò rí i pẹ̀lú ojúu wọn Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀, ẹ̀yin ahoro Jérúsálẹ́mù, nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó sì ti ra Jérúsálẹ́mù padà Olúwa yóò sí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ojú gbogbo orílẹ̀ èdè, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí ìgbàlà Ọlọ́run wa Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìnínyìí! Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan! Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúrò tàbí kí ẹ ṣáré lọ nítorí Olúwa ni yóò ṣíwájúu yín lọ, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín Kíyèsí i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọgbọ́n òun ni a ó gbé ṣókè tí a ó sì gbéga a ó sì gbé e lékè gidigidi Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bọlá fún un— ìwò ojú rẹ ni a ti bà jẹ́ kọjá ti ẹnìkẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀ èdè ká, àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítoríi rẹ̀ Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i, àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn Ta ni ó ti gba ìhìn in wa gbọ́ àti ta ni a ti fi apá Olúwa hàn fún Òun dàgbà ṣókè níwájúu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èhù, àti gẹ́gẹ́ bí i gbòngbo tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀ Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fàwá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀ tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́ríi rẹ̀ A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bọlá fún un rárá Lótìítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú, ṣíbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù, tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú Ṣùgbọ́n a ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedédé wa a pa á lára nítorí àìsòdodo wa ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lóríi rẹ̀, àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi múwa láradá Gbogbo wa bí àgùntàn, ti sìnà lọ, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀ Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀ gbogbo àìṣedédé wa A jẹ ẹ́ níyà, a sì pọ́n ọn lójú, ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀ a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà, àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀ Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ, ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè nítorí àìṣedédé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan, tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀ Ṣíbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á lára àti láti mú kí ó jìyà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé rẹ̀ yóò pẹ́ títí, àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀ Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn nípa ìmọ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedédé wọn Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára, nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀míi rẹ̀ fún ikú, tí a sì kà á mọ́ àwọn alárèékọjá Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárèékọjá Ògo Ọjọ́ Iwájú Ti Ṣíónì Kọrin, Ìwọ obìnrin àgàn, ìwọ tí kò tí ì bímọ rí búsí orin, ẹ hó fún ayọ̀, ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro ju ti ẹni tí ó ní ọkọ, ni Olúwa wí Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i, fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i, má ṣe dá a dúró sọ okùn rẹ di gígùn, mú òpo rẹ lágbára sí i Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn-ún àti sí òsì ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀ èdè, wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́ Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwee rẹ Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìwà-rópó rẹ mọ́ Nítorí Ẹlẹ́dáà rẹ ni ọkọ rẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ni Olùràpadà rẹ a sì pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé Olúwa yóò pè ọ́ padà à fi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ tí a sì bà lọ́kàn jẹ́ obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́, tí a sì wá já kulẹ̀ ni Olúwa wí Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò mú ọ padà wá Ní ríru ìbínú Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun Èmi yóò síjú àánú wò ọ́, ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Núà, nígbà tí mo búra pé àwọn omi Núà kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́ Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìnyìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́ Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá tí a sì sí àwọn òkè kékeré nídìí, Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò, ni Olúwa , ẹni tí ó síjú àánú wò ọ́ wí Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri tí a kò sì tù nínú, Èmi yóò fi òkúta tìróò kọ́ ọ àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú sáfírésì Èmi yóò fi rúbísì ṣe odiì rẹ, àwọn ẹnu ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún, àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀ Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀ Ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun Ìpayà la ó mú kúrò pátapáta kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ọ̀ mi ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ Kíyèsí i, Èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ tí ń fẹ́ iná èédú di èjò-iná tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò ṣe nǹkan, ìwọ yóò já ahọ́nkáhọ́n tó bá fẹ̀ṣùn kàn ọ́ kulẹ̀ Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa , èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi, ni Olúwa wí Ìpè Sí Awọn Tí Òrùngbẹ Ń Gbẹ Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òrùngbẹ ń gbẹ, ẹ wá sí ibi omi àti ẹ̀yin tí kò ní owó ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ! Ẹ wá ra wáìnì àti mílíìkì láìsí owó àti láìdíyelé Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn Tẹ́tísílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ mi gbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láàyè Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lúù rẹ, ìfẹ́ Òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dáfídì Kíyèsí i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn, olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn Lótìítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀ àti orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá, Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì nítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀ Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa , Òun yóò sì ṣàánú fún un, àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjìn ín jọjọ Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín, tàbí ọ̀nà yín a há máa ṣe ọ̀nà mi, ni Olúwa wí Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ àti èrò mi ju èrò yín lọ Gẹ́gẹ́ bí òjò àti sílóò ti wálẹ̀ láti ọ̀run tí kì í sì padà sí ibẹ̀ láì bomirin ilẹ̀ kí ó sì mú kí ó tanná kí ó sì rudi, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi mú irúgbìn fún afúnrúgbìn àti àkàrà fún ọ̀jẹun, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́, yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀ a ó sì daríi yín lọ ní àlàáfíà òkè ńlá ńlá àti kéékèèkéé yóò bú sí orin níwájúu yín àti gbogbo igi inú un pápá yóò máa pàtẹ́wọ́ Dípò igi ẹ̀gún ni igi páìnì yóò máa dàgbà, àti dípò ẹ̀wọ̀n, mítílì ni yóò yọ Èyí yóò wà fún òkìkí Olúwa , fún àmì ayérayé, tí a kì yóò lè parun Ìgbàlà Fún Àwọn Mìíràn Ohun tí Olúwa wí nìyìí Ẹ pa ìdájọ́ mọ́ ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà, nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí àti òdodo mi ni a ó fi hàn láìpẹ́ jọjọ Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí, ọkùnrin náà tí ó dì í mú ṣinṣin, tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bàá jẹ́, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀ mọ́ Olúwa sọ wí pé, Olúwa yóò yà mí ṣọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ Àti kí ìwẹ̀fà kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé Igi gbígbẹ lásán ni mí Nítorí pé ohun tí Olúwa wí nìyìí Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹ́ḿpìlì àti àgbàlá rẹ̀ ìrántí kan àti orúkọ kan tí ó sànju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé tí a kì yóò ké kúrò Àti àwọn àjèjì tí ó ṣo ara wọn mọ́ Olúwa láti sìn ín, láti fẹ́ orúkọ Olúwa àti láti foríbalẹ̀ fún un gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́ àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin— àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi Ọrẹ síṣun àti ẹbọ wọn ni a ó tẹ́wọ́gbà lóríi pẹpẹ mi nítorí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀ èdè Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ wí pé— ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Ísírẹ́lì jọ Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lúu wọn yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kó jọ Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú un pápá, ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run! Àwọn olùṣọ́ Ísírẹ́lì fọ́jú, gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀ Gbogbo wọn jẹ́ adití ajá, wọn kò lè gbó wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá, wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀ wọn kì í ní ànító Wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí kò ní òye olúkúlùkù ń yà sọ́nà ara rẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀ Wá, ni igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, fún mi ní ọtí wáìnì! Jẹ́ kí a mu ọtí bíà wa lámu yó ọ̀la yóò sì dàbí òní, tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ Ìtùnú Fún Àwọn Oníròbìnújẹ́ Olódodo ṣègbé kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀ a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ, kò sì sí ẹni tó yé pé a ti mú àwọn olódodo lọ láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi Gbogbo àwọn tí ń rìn déédéé ń wọ inú àlàáfíà wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn lókùú Ṣùgbọ́n ìwọ wá níhìnín, ìwọ ọmọ àjẹ́ yìí, ìwọ ìran panṣágà àti aṣẹ́wó! Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà Ta ni o ń yọ ṣùtì sí tí o sì yọ ahọ́n síta Ẹ̀yin kì í haá ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí, àti ìràn àwọn òpùrọ́ Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrin igi óákù àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀ ẹ fi àwọn ọmọ yín rúbọ nínú kòtò jínjìn àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta Àwọn ère tí ó wà ní àárin òkúta dídán wọ̀n n nì, nínú kòtò jínjìn ni ìpín in yín àwọn, àwọ̀n ni ìpín in yín Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀ àti láti ta ọrẹ oníhóró Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ kí n dáwọ́ dúró Ìwọ ti ṣe bẹ́ẹ̀dì rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sí bẹ́ẹ̀dì yín sílẹ̀, ẹ gun oríi rẹ̀ lọ, ẹ sì sí i sílẹ̀ gbagada ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn bẹ́ẹ̀dì wọn, ẹ̀yin sì ń wo ìhòòhò wọn Ẹ̀yin lọ sí Mólẹ́kì pẹ̀lú òróró ólífì ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú! Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ baa yín, ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, kò sí ìrètí mọ́ Ẹ rí okun kún agbára yín, nípá bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ọ yín Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù tí ẹ fi ń ṣèké sí mi, àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín Ǹjẹ́ kì í ṣe nítoríi dídákẹ jẹ́ ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́ tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi Èmi yóò sí òdodo yín payá àti iṣẹ́ẹ yín, wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín! Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ, èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀ ni yóò jogún ilẹ̀ náà yóò sì jogún òkè mímọ́ mi A ó sì sọ wí pé Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe! Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀ṣẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́ Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí Èmi kì yóò fẹ̀ṣùn kan ni títí láé, tàbí kí n máa bínú ṣá á, nítorí nígbà náà ni ọkàn ọmọnìyàn yóò rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi èémí ọmọnìyàn tí mo ti dá Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúà rẹ̀ mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojúù mi pamọ́ ní ìbínú ṣíbẹ̀, ó tẹ̀ṣíwájú nínú tinú-mi-ni-n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀ Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn Èmi yóò tọ́ ọ sọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá, ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Ísírẹ́lì Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí, ni Olúwa wí, Àti pé Èmi yóò wo wọ́n sàn Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru òkun tí kò le è sinmi, tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè Kò sí àlàáfíà, ni Ọlọ́run mi wí, fún àwọn ìkà Ààwẹ̀ Tòótọ́ Kígbe rẹ̀ ṣókè, má ṣe fà ṣẹ́yìn Gbé ohùn rẹ ṣókè bí i ti fèrè Jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún áwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn àti fún ilé Jákọ́bù ẹ̀ṣẹ̀ wọn Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi, àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀ èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà tí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀ Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkan wọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀, ni wọ́n wí, tí ìwọ kò sì tí ì rí Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀, tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ní ọjọ́ ààwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yín ẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú Ààwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀, àti lílu ọmọnìkejì ẹni pẹ̀lú ẹṣẹ́ ìkà Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìí kí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga Ǹjẹ́ èyí ha ni irú ààwẹ̀ tí mo yàn bí, ọjọ́ kanṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ Í haá ṣe kí ènìyàn tẹ orí i rẹ̀ ba bí i koríko láṣán ni bí àti ṣíṣùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀ nìyí, ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa Ǹjẹ́ irú ààwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìsòdodo àti láti tú gbogbo okùn àjàgà, láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀ àti láti fọ́ gbogbo àjàgà Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòsì tí ń rìn káàkiri nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòòhò, láti daṣọ bò ó, àti láti má ṣe lé àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran yín sẹ́yìn Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀ àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájúù rẹ, ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé Èmi nìyí Bí ẹ̀yin bá mú àjàgà aninilára kúrò, pẹ̀lú ìka àléébù nínà àti ọ̀rọ̀ ìṣáátá, àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn, nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn, àti òru yín yóò dàbí ọ̀ṣán-gangan Olúwa yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo òun yóò tẹ́ gbogbo àìní ìn yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí òòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀ yóò sì fún egungun rẹ lókun Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáadáa, àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í tán Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro ìṣẹ̀ǹbáyé kọ́ wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ ró a ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wó àti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú un rẹ̀ Bí ìwọ bá pa ẹṣẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́-ìsinmi jẹ́, àti síse bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi, bí ìwọ bá pe ọjọ-ìsinmi ní ohun dídùn àti ọjọ́ mímọ́ Olúwa ní ohun ọ̀wọ̀ àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọ àti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbí kí o máa ṣọ̀rọ̀ òòrayè, nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú Olúwa rẹ, èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé, àti láti máa jàdídùn ìní ti Jákọ́bù baba rẹ Ẹnu Olúwa ni ó ti sọ̀rọ̀ Ẹ̀ṣẹ̀, Ìjẹ́wọ́ Àti Ìràpàdà Lódodo ọwọ́ Olúwa kò kúrú láti gbàlà, tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́ Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojúu rẹ̀ pamọ́ fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́ Nítorí ọwọ́ọ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀, àti ìka ọwọ́ọ yín fún ẹ̀bi Ètèe yín ń pa irọ́ púpọ̀, ahọ́n an yín sì ń ṣọ̀rọ̀ nǹkan ibi Kò sí ẹni tí ó bèèrè fún ìdájọ́ òdodo kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́ Wọ́n gbọ́kànlé àwíjàre aṣán àti ọ̀rọ̀ irọ́ wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà Wọn ń pa ẹyín pamọ́lẹ̀ wọn sì ń ta owú aláǹtakùn Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú, àti nígbà tí a pa ọ̀kan, pamọ́lẹ̀ ni ó jáde Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdàkú sì kún ọwọ́ wọn Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe àmì ọ̀nà wọn Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀ kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọn wọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ́rọ, kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa, àti tí òdodo kò fi tẹ̀wá lọ́wọ́ A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ jẹ́ òkùnkùn fún ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri tí a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni láàrin alágbára àwa dàbí òkú Gbogbo wa là ń ké bí i bíárì àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbà A ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí à ń wọ̀nà fún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa, àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa, ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa , kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run, dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀, pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbérò síta Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo ṣẹ́yìn, àti ti òdodo dúró lókèèrè òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà, òdodo kò sì le è wọlé A kò rí òtítọ́ mọ́, àti ẹni tí ó bá sá ibi tì di ìjẹ Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ pé kò sí ìdájọ́ òdodo Òun rí i pé kò sí ẹnìkan, àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́ nítorí apá òun tìkálárarẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀, àti òdodo òun tìkálára rẹ̀ ló gbé e ró Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàya rẹ̀, àti àsíborí ìgbàlà ní oríi rẹ̀ ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀ ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣan án ìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ òun yóò ṣan án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa , àti láti ìlà oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀ Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi èyí tí èémí Olúwa ń tì lọ Olùdáǹdè yóò wá sí Ṣíhónì, sí àwọn tí ó wà ní Jákọ́bù tí ó ronúpìwàdá ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ni Olúwa wí Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí, ni Olúwa wí, Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé ni Olúwa wí Ìpè Sí Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Àìṣáyà Ní ọdún tí ọba Hùṣáyà kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sì kún inú tẹ́ḿpìlì Àwọn Ṣéráfù wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹṣẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ ogun gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀ Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹ́ḿpìlì sì kún fún èéfín Ègbé ni fún mi! Ni mo ké, Mo ti gbé! Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrin àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ Lẹ́yìn náà, ọ̀kan nínú àwọn Ṣéráfù wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ́-iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní oríi pẹpẹ Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, Wòó, èyí ti kan ètè rẹ a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù Lẹ́yìn náà, mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, Ta ni n ó rán Ta ni yóò sì lọ fún wa Èmi sì wí pé, Èmi nìyí, rán mi! Òun sì wí pé, Tọ àwọn ènìyàn mi lọ kí o sì wí pé  Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín ní rírí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì, mú kí wọn kútí kí o sì pa ojú wọn dé Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò fi ojú u wọn ríran, ki wọn má ba à fi etíi wọn gbọ́ràn, kí òye máa ba à yé wọn ní ọkàn an wọn kí wọn má ba à yípadà kí a má ba à sì wò wọ́n sàn Nígbà náà ni mo wí pé, Báwo ni yóò ti pẹ́ tó Olúwa Òun sì dáhùn pé Títí tí gbogbo ìlú ńlá yóò fi dahoro láìsí olùgbé nínú un rẹ̀ mọ́, títí tí gbogbo ilé yóò fi di ìkọ̀sílẹ̀ tí gbogbo ilé yóò sì di àlàpà àti ahoro, títí tí Olúwa yóò fi rán gbogbo wọn jìnnà réré tí ilẹ̀ náà sì di ìkọ̀sílẹ̀ pátapáta Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ náà, yóò sì tún pàpà padà parun Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí igi tẹ́rẹ́bíńtì àti óákù ti í fi kùkùté sílẹ̀ nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni irúgbìn mímọ́ náà yóò di kùkùté ní ilẹ̀ náà Ògo Ṣíhónì Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, ògo Olúwa sì ràdọ̀bò ọ́ Kíyèsí i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé òkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́ ògo rẹ̀ sì farahàn lóríi rẹ Àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ, àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ Gbé ojú rẹ ṣókè kí o sì wò yíká rẹ Gbogbo wọn gbárajọ wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ àwọn ọmọ rẹ wá láti ọ̀nà jíjìn, àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrìn rẹ ni a gbé ní apá Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán, ọkàn rẹ yó fó yó sì kún fún ayọ̀ ọrọ̀ inú òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ, sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá Ọ̀wọ́ ràkunmí yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀dọ́ ràkunmí Mídíánì àti Ẹfà Àti gbogbo wọn létí Ṣèbà yóò wá, wọn yóò mú Góòlù àti tùràrí lọ́wọ́ tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa Gbogbo agbo ẹran Kédárì ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ, àwọn àgbò ti Nébáíótì yóò sìn ọ́ wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lóríi pẹpẹ mi, bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹ́ḿpìlì ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́ Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kùrukùru, gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn Lótìítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Táṣíṣì mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn, pẹ̀lú fàdákà àti góòlùu wọn, fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́ Àwọn àjèjì yóò tún ògiriì rẹ mọ àwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́ Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́, ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ Gbogbo ẹnu bodè rẹ ni yóò wà ní sísí sílẹ̀, a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè wá tí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun Nítorí pé orílẹ̀ èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun pátapáta ni yóò sì dahoro Ògo Lẹ́bánónì yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, igi páínì, fírì àti ṣípírẹ́sì papọ̀, láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò wá foríbalẹ̀ fún ọ gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ wọn yóò sì pè ọ́ ní Ìlú Olúwa , Ṣíhónì ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kóríra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá, Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé àti ayọ̀ àtìrandíran Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀ èdè a ó sì rẹ̀ ọ́ ni ọmú àwọn ayaba Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi Olúwa , èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jákọ́bù Nnì Dípò búróǹsì, èmi ó mú wúrà wá fún ọ, àti fàdákà dípò irun Dípò igi yóò mú búróńsì wá, àti irun dípò òkúta Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe gómínà rẹ àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́, tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlà àti àwọn ẹnu bodè rẹ ní ìyìn Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́, tàbí kí ìtànsán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́, nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé, àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́, àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́ Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ, àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé Àwọn ni èhù tí mo ti gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, láti fi ọlá ńlá mi hàn Èyí tí ó kéré jù nínú un yín yóò di ẹgbẹ̀rún kan, èyí tí ó kéré yóò di orílẹ̀ èdè ńlá Èmi ni Olúwa ní àkókò rẹ̀ Èmi yóò ṣe èyí kánkán Ọdún Ojúrere Ẹ̀mí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà lára mi nítorí Olúwa ti fi àmì-òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn talákà Ó ti rán mi láti ṣe àwòtan oníròbìnújẹ́ láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n, Láti kéde ọdún ojúrere Olúwa àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa, láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú, àti láti pèṣè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Ṣíhónì láti dé wọn ládé ẹ̀yẹ dípò eérú, òróró ìdùnnú dípò ìbànújẹ́, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúùru ọkàn A ó sì pè wọ́n ní óákù òdodo, irúgbìn Olúwa láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn Wọn yóò tún àwọn ahoro ìṣẹ̀ǹbáyé kọ́ wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́tijọ́ náà bọ̀ sípò wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa , a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo Dípò àbùkù wọn àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po-méjì, àti dípò àbùkù wọn wọn yóò yọ̀ nínú ìníi wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn, ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ ti wọn Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀ Ní òtítọ́ mi èmi yóò ṣẹ̀san fún wọn èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lúu wọn A ó mọ ìrandíran wọn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè àti àwọn ìran wọn láàrin àwọn ènìyàn Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe oríi rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà, àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú èhù jáde àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà, Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀ èdè Orúkọ Ṣíhónì Tuntun Nítorí Ṣíhónì èmi kì yóò dákẹ́, nítorí i Jérúsálẹ́mù èmi kì yóò sinmi ẹnu, títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀, àti ìgbàlà rẹ̀ bí i tọ́ọ̀sì tí ń jó geregere Àwọn orílẹ̀ èdè yóò rí òdodo rẹ, àti gbogbo ọba ògo rẹ a ó sì máa pè ọ́ ní orúkọ mìíràn èyí tí ẹnu Olúwa yóò fi fún un Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ Olúwa , adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́ tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfísíbà, àti ilẹ̀ rẹ ní Béúlà nítorí Olúwa yóò yọ́nú sí ọ àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwó bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwó Gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lóríì rẹ Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jérúsálẹ́mù wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru Ẹ̀yin tí ń ké pe Olúwa , ẹ má ṣe fún ra yín ní ìsinmi, àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmi títí tí yóò fi fi ìdí Jérúsálẹ́mù múlẹ̀ tí yóò sì fi òun ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé Olúwa ti búra pẹ̀lú ọ̀tún rẹ̀ àti nípa agbára apá rẹ Èmi kì yóò jẹ́ kí hóró rẹ di oúnjẹ fún ọ̀tá rẹ bẹ́ẹ̀ ni àwọn àjèjì kì yóò mu wáìnì tuntun rẹ mọ́ èyí tí ìwọ ti ṣe làálàá fún ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá kóórè rẹ̀ ni yóò jẹ ẹ́ tí wọn ó sì yin Olúwa , àti àwọn tí wọ́n bá kó gírépù jọ ni wọn ó mú un nínú àgbàlá ilé mímọ́ mi Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà! Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn Ẹ mọ ọ́n, ẹ mọ ojú ọ̀nà òpópó! Ẹ sa òkúta kúrò Ẹ gbé àṣíá ṣókè fún àwọn orílẹ̀ èdè Olúwa ti ṣe ìkéde títí dé òpin ilẹ̀ ayé Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Ṣíhónì pé, kíyèsí i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀! Kíyèsí i, èrè ń bẹ pẹ̀lúu rẹ̀, àti ẹ̀san rẹ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn   A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́, ẹni ìràpadà Olúwa a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri, Ìlú tí a kì yóò kọ̀ sílẹ̀ Ọjọ́ Ẹ̀san Àti Ìràpadà Ọlọ́run Ta nì yìí tí ó ń bọ̀ láti Édómù, láti Bósírà, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí osùn ṣe àbàwọ́n fún Ta nì yìí, tí a wọ̀ ní aṣọ ẹ̀yẹ, tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀ Èmi ni bí, tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo tí ó nípa láti gbàlà Èéṣe tí aṣọ yín fi pupa gẹ́gẹ́ bí i tàwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfúntí Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì láti àwọn orílẹ̀ èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi Mo tẹ̀wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mi mo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú mi ẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi, mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi Nítorí ọjọ́ ẹ̀san wà ní ọkàn mi àti pé ọdún ìràpadà mi ti dé Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́ Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́ nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún mi àti ìrunú mi ni ó gbémiró Mo tẹ orílẹ̀ èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mu mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀ Èmi yóò sọ nípa àánú Olúwa ìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Olúwa ti ṣe fún wa bẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo tí ó ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀ Ó wí pé, Lótítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn Nínú un gbogbo ìpọ́njúu wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́ àti ańgẹ́lì tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là Nínú Ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà ó gbé wọn ṣókè ó sì pọ̀n wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ wọ́n sì ba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà ó sì di ọ̀ta wọn òun tìkálára rẹ̀ sì bá wọn jà Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì, àwọn ọjọ́ Mósè àti àwọn ènìyàn rẹ̀ níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la òkun já, pẹ̀lú olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran rẹ̀ Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn, ta ni ó rán ògo apá ti agbára rẹ̀ láti wà ní apá ọ̀tún Mósè, ta ni ó pín omi níyà níwájú wọn, láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀, ta ni ó ṣíwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko, a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí Olúwa Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yín láti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí i láti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo Níbo ni ipá àti agbára rẹ wà Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni a tí mú kúrò níwájúu wa Ṣùgbọ́n ìwọ ni Baba wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù kò mọ̀ wá tàbí Ísírẹ́lì mọ ẹni tí à á ṣe ìwọ, Olúwa ni Baba wa, Olùràpadà wa láti ìgbà n nì ni orúkọ rẹ Èéṣe Olúwa tí o fi jẹ́ kí a ṣáko kúrò ní ojú ọ̀nà rẹ tí o sì ṣé àyà wa le tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi bọ̀wọ̀ fún ọ Padà nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ẹ̀yà tíi ṣe ogún ìní rẹ Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ fi gba ibi mímọ́ rẹ, ṣùgbọ́n nísinsìn yìí àwọn ọ̀tá wa ti tẹ ibi mímọ́ rẹ mọ́lẹ̀ Àwa jẹ́ tìrẹ láti ìgbà n nì ṣùgbọ́n ìwọ kò tí ì jọba lé wọn lórí, a kò sì tí ì pè wọ́n mọ́ orúkọ rẹ Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì ṣọ̀kalẹ̀ wá, tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ! Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó tí ó sì mú kí omi ó hó, ṣọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mímọ̀ fún àwọn ọ̀ta rẹ kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ! Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí, o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ Láti ìgbà ìwásẹ̀ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ, kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ, tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fi ayọ̀ ṣe ohun tótọ́, tí ó rántí ọ̀nà rẹ Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn, inú bí ọ Báwo ni a ó ṣe gbà wá là Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́, gbogbo òdodo wa sì dàbí èkíṣà ẹlẹ́gbin gbogbo wa kákò bí ewé, àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, Olúwa , ìwọ ni Baba wa Àwa ni amọ̀, ìwọ ni ọ̀mọ gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ Má ṣe bínú kọjá ààlà, Ìwọ Olúwa Má ṣe rántíi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà, nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa Àwọn Ìlú Mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀ Ṣíhónì pàápàá aṣálẹ̀ ni, Jérúsálẹ́mù ibi ìkọ̀sílẹ̀ Tẹ́ḿpìlì Mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́, ni a ti fi iná sun, àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Olúwa , ìwọ ó ha sì tún fara rẹ pamọ́ bí Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹwá kọjá ààlà bí Ìdájọ́ Àti Ìgbàlà Èmi fi ara mi hàn fún àwọn tí kò béèrè fún mi Àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi Sí àwọn orílẹ̀ èdè tí kò pe orúkọ mi, Ni èmi wí pé, Èmi nìyìí, Èmi nìyìí Gbogbo ọjọ́ ni mo ti nawọ́ mi síta sí àwọn ènìyàn ọlọ́rùn líle, tí wọn ń rìn lọ́nà tí kò dára, tí wọ́n sì gbáralé èrò ara wọn àwọn ènìyàn tí wọ́n bí mi nínú nígbà gbogbo lójú ara mi gan an, wọ́n ń rúbọ nínú ọgbà wọ́n sì ń ṣun tùràrí lóríi pẹpẹ bíríkì wọ́n ń jókòó láàrin ibojì wọ́n sì ń lo òru wọn nínú ìṣọ́ ìkọ̀kọ̀ tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀, tí ìkòkò ọbẹ̀ wọn kún fún ẹran àìmọ́ tí ó wí pé, Ẹ sún mẹ́yìn ẹ má wá sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti jẹ́ mímọ́ jù fún un yín! Àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èéfín nínú ihò imú mi iná tí ń fi gbogbo ọjọ́ jó Kíyèsí i, a ti kọ ọ́ síwájúu mi Èmi kì yóò dákẹ́, ṣùgbọ́n n ó san án padà lẹ́kùn ún rẹ́rẹ́ Èmi yóò san án padà ní itan wọn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín àti tàwọn baba yín, ni Olúwa wí Nítorí pé wọ́n sun ẹbọ ní orí òkè ńlá wọ́n sì ṣe mí lẹ́gbin ní òkè kékeré, Èmi yóò wọ́n ọ́n sí wọn nítan ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀san ohun gbogbo tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀ Ohun tí Olúwa wí nìyìí Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí òjé sì tún wà nínú àpólà gírépù tí àwọn ènìyàn sì wí pé, má ṣe bà á jẹ́, ohun dáradára sì kù sínú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jákọ́bù, àti láti Júdà àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n ọn nì àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn, ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé Ṣárónì yóò di pápá oko fún ọ̀wọ́ ẹran, àti àfonífojì Ákò yóò di ibi ìsinmi fún agbo ẹran, fún àwọn ènìyàn mi tí ó wá mi Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó kọ Olúwa sílẹ̀ tí ẹ sì gbàgbé òkè mímọ́ mi, tí ó tẹ́ tábìlì fún ọrọ̀ tí ẹ sì kún abọ́ pẹ̀lú ọtí wáìnì fún àtubọ̀tán, Èmi yóò yà ọ́ ṣọ́tọ̀ fún idà, àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn Mo ṣọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tísílẹ̀ Ẹ̀yin ṣe búrurú ní ojú mi ẹ sì yan ohun tí ó bàmí lọ́kàn jẹ́ Nítorí náà ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí nìyìí Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ẹ̀yin, àwọn ìránṣẹ́ mi yóò mu, ṣùgbọ́n òrùngbẹ yóò máa gbẹ ẹ̀yin àwọn ìránṣẹ́ mi yóò ṣe àjọyọ̀, ṣùgbọ́n a ó dójú ti ẹ̀yin Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrin láti inú ayọ̀ ọkàn wọn wá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe sókè láti inú ìrora ọkàn yín àti ìpohùnréré ní ìròbìnújẹ́ ọkàn Ẹ̀yin yóò fi orúkọ yín sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ègún Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sì pa yín, ṣùgbọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni òun yóò fún ní orúkọ mìíràn Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náà yóò ṣe é nípaṣẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́ Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náà yóò búra nípaṣẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́ Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbé yóò sì farasin kúrò lójú mi Kíyèsí i, Èmi yóò dá àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́, tàbí kí wọn wá sí ọkàn Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá, nítorí èmi yóò dá Jérúsálẹ́mù láti jẹ́ ohun ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀ Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jérúsálẹ́mù n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi ariwo ẹkún àti igbe ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́, títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀, tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan ni a ó pè ní ẹni ìfibú Wọn yó kọ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọn wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èṣo wọn Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmìíràn láti gbé, tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmìíràn láti jẹ, Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan, bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún ìgbà pípẹ́ Wọn kì yóò ṣe wàhálà lásán tàbí kí wọn bímọ tí ọjọ́ iwájú wọn kì yóò sunwọ̀n nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti Olúwa bùkún fún, àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́ Ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn yóò jẹun pọ̀, kìnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò Wọn kì yóò panilára tàbí panirun ní gbogbo òkè mímọ́ mi, ni Olúwa wí Ìdájọ́ Àti Ìrètí Ohun tí Olúwa wí nìyìí Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni àpótí ìtìṣẹ mi, Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà ni Olúwa wí Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí ẹni náà tí ó rẹrarẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀, tí ó sì wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rúbọ ó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kan àti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́ àgùntàn kan tọrẹ, dàbí ẹni tí ó kán ajá kan lọ́rùn ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbin oníhóró tọrẹ dàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá, ẹni tí ó bá sì ṣun tùràrí ìrántí, dàbí ẹni tí ó sin ère òrìṣà Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tiwọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn Fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọn n ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn, nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tísílẹ̀ Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú mi wọ́n sì yan ohun tí mo kóríìra rẹ̀ Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa , Ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípaṣẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kóríra yín, tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé, Jẹ́ kí a yin Olúwa lógo, kí a le rí ayọ̀ yín! Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì Gbọ́ rògbòdìyàn n nì láti ìlú wá, gbọ́ ariwo náà láti tẹ́ḿpìlì wá! Ariwo tí Olúwa ní í ṣe tí ó ń san án fún àwọn ọ̀ta rẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí wọn Kí ó tó lọ sí ìrọbí, ó ti bímọ kí ó tó di pé ìrora dé bá a, ó ti bí ọmọkùnrin Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀ èdè kan níjọ́ kan tàbí kí orílẹ̀ èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan Síbẹ̀síbẹ̀ Ṣíhónì bẹ̀rẹ̀ rírọbí tàìrọbí bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀ Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọ́bí kí èmi má sì mú ni bí ni Olúwa wí Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ nígbà tí mo ń mú ìbí wá ni Ọlọ́run yín wí Ẹ bá Jérúsálẹ́mù yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀ ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ọmú rẹ̀ tí ó túnilára Ẹ̀yin yóò mu àmuyó ẹ ó sì gbádùn nínú à-kún-wọ́-sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀ Nítorí ohun tí Olúwa wí nìyìí Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò àti ọrọ̀ orílẹ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀ a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú a ó sì tù yín nínú lórí Jérúsálẹ́mù Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú un yín yóò dùn ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mímọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ Kíyèsí i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú iná àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle òun yóò mú ìbínú rẹ ṣọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú, àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná Nítorí pẹ̀lú iná àti idà ni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lóríi gbogbo ènìyàn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrin àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀, ni Olúwa wí Àti Èmi, nítorí ìgbéṣẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn òrílẹ̀ èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi Èmi yóò sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè Táṣíṣì, sí àwọn ará Líbíyà àti Lídíyà , sí Túbálì ati ará Gíríkì, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnàréré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi Wọn yóò kéde ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀ èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti wágùnnù, àti lórí ìbáaka àti ràkúnmí, ni Olúwa wí Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú tẹ́ḿpìlì Olúwa nínú ohun èlò mímọ́ Àti pé èmi yóò sì yan àwọn kan nínú wọn pẹ̀lú láti jẹ́ àlùfáà àti Léfì, ni Olúwa wí Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí mo dá yóò ṣe faradà á níwájú mi, ni Olúwa wí, Bẹ́ẹ̀ ni orúkọ yín àti ìrandíran yín yóò pegedé Láti oṣù tuntun kan dé òmíràn àti láti ọjọ́ ìsinmi kan dé òmíràn, ni gbogbo ọmọnìyàn yóò wá, wọn yóò sì tẹríba níwájú mi, ni Olúwa wí Wọn yóò sì jáde lọ wọn yóò sì lọ wo òkú àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ sí mi kòkòrò wọn kì yóò kú, bẹ́ẹ̀ ni iná wọn ni a kì yóò pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jẹ́ ohun ìríra fún gbogbo ọmọ ènìyàn Àmì Ti Ìmánúẹ̀lì Nígbà tí Áhásì ọmọ Jótamù ọmọ Hùṣáyà jẹ́ ọba Júdà, ọba Résínì ti Árámù àti Pẹ́kà ọmọ Rẹ̀málíà ọba Ísírẹ́lì gòkè wá láti bá Jérúsálẹ́mù jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀ Báyìí, a sọ fún ilé Dáfídì pé, Árámù mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Éfáímù fún ìdí èyí, ọkàn Áhásì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́ Lẹ́yìn èyí, Olúwa sọ fún Àìṣáyà pé, Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣéárì-Jáṣúbù láti pàdé Áhásì ní ìpẹ̀kun ìṣàn-omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀ Sọ fún un, Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítoríi kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Résínì àti Árámù àti ti ọmọ Rẹ̀málíà Árámù, Éfáímù àti Rèmálíà ti dìtẹ̀ ìparun rẹ, wọ́n wí pé, Jẹ́ kí a kọlu Júdà jẹ́ kí a fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kí a sì pín in láàrin ara wa, kí a sì fi ọmọ Tábẹ́lì jọba lóríi rẹ̀ Ṣíbẹ̀ èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí  Èyí kò ní wáyé Èyí kò le ṣẹlẹ̀, nítorí Dámásíkù ni orí Árámù, orí Dámásíkù sì ni Résínì Láàrin ọdún márùnlélọ́gọ́ta Éfáímù yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́ Ṣamaríà ni orí fún Éfáímù, ẹni tí ó sì jẹ́ orí Samaríà náà ni ọmọ Rèmálíà   Bákan náà Olúwa tún bá Áhásì sọ̀rọ̀, Béèrè fún ààmì lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, bóyá ní ọ̀gbun tí ó jìn jùlọ tàbí àwọn òkè tí ó ga jùlọ Ṣùgbọ́n Áhásì sọ pé, Èmi kì yóò béèrè Èmi kò ní dán Olúwa wò Lẹ́yìn náà Àìṣáyà sọ pé, Gbọ́ ní ìsinsìnyí, ìwọ ilé Dáfídì, kò ha tọ́ láti tan ènìyàn ní ṣùúrù, o ó ha tan Ọlọ́run ní ṣùúrù bí Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní àmì kan Wúndíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan àre Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan àre, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro Olúwa yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Éfáímù ti yà kúrò ní Júdà, yóò sì mú ọba Áṣíríà wá Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò súfèé pe àwọn eṣinṣin láti àwọn odò tó jìnnà ní Éjíbítì wá, àti fún àwọn oyin láti ilẹ̀ Áṣíríà Gbogbo wọn yóò sì wá dó sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti pàlàpálá òkúta, lára koríko ẹ̀gún àti gbogbo ibi ihò omi Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò lo abẹfẹ́lẹ́ tí a yá láti ìkọjá odò, ọba Ásíríà, láti fá irun orí àti ti àwọn ẹsẹ̀ẹ yín, àti láti mú irùngbọ̀n yín kúrò pẹ̀lú Ní ọjọ́ náà, ọkùnrin kan yóò máa sin ọ̀dọ́ màlúù kan àti ewúrẹ́ méjì Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọn yóò máa fún un, yóò ní wàràǹkàsì láti jẹ Gbogbo àwọn tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà yóò jẹ wàràǹkàsì àti oyin Ní ọjọ́ náà, ni gbogbo ibi tí àjàrà tí ó tó ti ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà, ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n nìkan ni yóò wà níbẹ̀ Àwọn ènìyàn yóò máa lọ ṣíbẹ̀ pẹ̀lú ọrun àti ọfà nítorí pé ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n ni yóò bo gbogbo ilẹ̀ náà Fún àwọn òkè tí a ti ń fi ọkọ́ ro nígbà kan rí, ẹ kò ní lọ ṣíbẹ̀ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n, wọn yóò di ibi tí a ń tú agbo ẹran sí, àti ibi tí àwọn àgùntàn ti ń sáré Ásíríà, Ohun-èlò Olúwa sọ fún mi pé, mú ìwé ńlá kan, kí o sì fi pẹ́ẹ́nì lásán kọ Maha-Ṣalali-Haṣi-Baṣì Èmi yóò sì pe Hùráyà, Àlùfáà àti Ṣekaráyà ọmọ Jébérékíà gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí tí ó ṣeé gbọ́kànlé fún mi Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì-obìnrin náà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan Olúwa sì wí fún mi pé, pe orúkọ rẹ̀ ní Maha-Ṣalali-Haṣi-Baṣì Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé Baba mi tàbí Ìyá mi gbogbo ọrọ̀ Dámásíkù àti ìkógun ti Ṣamáríà ni ọba àwọn Áṣíríà yóò ti kó lọ Olúwa sì tún sọ fún mi pé Nítorí pé àwọn ènìyàn ti kọ omi Ṣílóà tí ń ṣàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí wọ́n sì láyọ̀ lórí Réṣínì àti ọmọ Rẹ̀málíà, fún ìdí èyí, Olúwa fẹ́ mú wá sóríi wọn agbára ìkún omi odò ọba Ásíríà àti ògo rẹ̀ yóò sì bo gbogbo àyasíi rẹ̀ gbogbo bèbè di bíbò mọ́lẹ̀ yóò sì gbá rìẹrìẹ dé Júdà, a gba orí ẹ̀ lọ, yóò gba ibẹ̀ lọ yóò sì mú un dọ́run Ìyẹ́ apá rẹ̀ tí ó nà yóò bo gbogbo ìbú ilẹ̀ náà Ìwọ Ìmánúẹ́lì Ké ariwo ogun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí a sì fọ́ọ yín túútúúú, fetísílẹ̀, ẹ̀yin ilẹ̀ jínjìn réré Ẹ palẹ̀mọ́ fún ogun, kí a sì fọ́ ọ túútúúú! Ẹ hun ète yín, yóò di títúká Ẹ gbérò ètò náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lúu wa Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ lórí mi pẹ̀lú ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí Ó wí pé Má ṣe pe éyí ní ọ̀tẹ̀ ohun gbogbo tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá pè ní ọ̀tẹ̀, má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù, má sì ṣe fòyà rẹ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ẹni tí ìwọ yóò kà sí mímọ́, Òun ni kí o bẹ̀rù Òun ni kí àyà rẹ̀ fò ọ́, Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́ ṣùgbọ́n fún ilé Ísírẹ́lì méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọṣẹ̀ àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú àti fún àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ni yóò jẹ́ tàkúté àti ẹ̀bìtì Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni yóò kọṣẹ̀, wọn yóò ṣubú wọn yóò sì fọ́ yángá, okùn yóò mú wọn, ọwọ́ yóò sì tẹ̀ wọ́n Di májẹ̀mú náà kí o sì fi èdìdì di òfin náà láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi Èmi yóò dúró de Olúwa , ẹni tí ó ń fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún ilé Jákọ́bù Mo fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sínú rẹ Èmi nìyí, àti àwọn ọmọ tí Olúwa fi fún mi Àwa jẹ́ àmì àti àpẹẹrẹ ní Ísírẹ́lì láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ẹni tí ó ń gbé ní òké Síhónì Nígbà tí àwọn ènìyàn bá sọ fún un yín pé kí ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn abókúsọ̀rọ̀ àti àwọn Oṣó, ti máa ń kún tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ǹjẹ́ kò ha yẹ kí àwọn ènìyàn béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wọn bí Èéṣe tí ẹ fi ń bá òkú sọ̀rọ̀ ní orúkọ alààyè Sí òfin àti májẹ̀mú! Bí wọn kò bá sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò ní ìmọ́lẹ̀ ọjọ́ Pẹ̀lú ìpọ́njú àti ebi, ni wọn yóò máa rin ilẹ̀ náà ká, nígbà tí ebi bá pa wọ́n, nígbà yìí ni inú yóò bí wọn, wọn yóò síjú wòkè, wọn yóò sì ṣépè lé àwọn ọba àti ọlọ́run wọn Nígbà náà ni wọn yóò síjú wolẹ̀, wọn yóò sì rí ìpọ́njú, òkùnkùn àti ìpòrúúrù tí ó bani lẹ́rù, a ó sì sọ wọ́n sínú òkùnkùn biribiri A Bí Ọmọ Kan Fún Wa Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, kò ní sí ìpòrúurù kan kan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́ Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sẹbúlúnì sílẹ̀ àti ilẹ̀ Nápítalì pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Gálílì ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jọ́dánì Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá Lórí àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ òjìji ikú ni ìmọ́lẹ̀ ti ràn Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá wọ́n sì yọ̀ níwájúu rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkóórè, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀ nígbà tí à ń pín ìkógun Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Mídíánì, ìwọ ti fọ́ ọ túútúúú àjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù, ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn, ọ̀gọ aninilára wọn Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun àti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀, ni yóò wà fún ìjóná, àti ohun èlò iná dídá Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa, ìjọba yóò sì wà ní èjìkáa rẹ̀ A ó sì má a pè é ní Ìyanu Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà Ní ti ìgbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun Yóò jọba lórí ìtẹ́ Dáfídì àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo, nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀, pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyi ṣẹ Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jákọ́bù Yóò sì wá sórí Ísírẹ́lì Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n— Éfáímù àti gbogbo olùgbé Ṣamáríà— tí ó sọ pẹ̀lú ìgbéraga àti gààrù àyà pé Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀ ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán, a ti gé àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ lulẹ̀ ṣùgbọ́n igi kédárì ní a ó fí dípò wọn Ṣùgbọ́n Olúwa fún àwọn ọ̀ta Réṣínì ní agbára láti dojúkọ wọ́n ó sì ti rú àwọn ọ̀ta wọn ṣókè Àwọn Árámínì láti ìlà-oòrùn àti Fílístínì láti ìwọ̀ oòrùn wọ́n si fi gbogbo ẹnu jẹ́ Ìsirẹli run Ní gbogbo èyí ìbínú un rẹ̀ kò yí kúrò Ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde ṣíbẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà sí ẹni náà tí ó lù wọ́n bẹ́ẹ̀ ní wọ́n kò wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun Nítorí náà ni Olúwa yóò ṣe ké àti orí àti ìrù kúrò ní Ísírẹ́lì, àti Imọ̀-ọ̀pẹ àti koríko-odò ní ọjọ́ kanṣoṣo, Àwọn alàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ni orí, àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí sì wọ́n lọ́nà Àwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó, nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ́ Ọlọ́run, ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde Ṣíbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró Nítòótọ́ ìkà ń jóni bí iná, ó ń jó àtẹ̀wọ̀n, àtẹ̀gùn run, ó sì ń dáná sun ìgbẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ń yí lọ sókè ní ọ̀wọ̀n èéfín Nípaṣẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná, ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun, síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n, ní apá òsì, wọn yóò jẹ ṣùgbọ́n, kò ní tẹ́wọn lọ́rùn Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara ọmọ rẹ̀ Mánásè yóò máa jẹ Éfáímù, nígbà tí Éfáímù yóò jẹ Mánásè wọn yóò parapọ̀ dojúkọ Júdà Ṣíbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúrò Ọwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró Àwọn Ìṣòro Àti Àwọn Ìdẹwò Jákọ́bù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ti Jésù Kírísítì Olúwa, Sí àwọn ẹ̀yà méjìlá tí ó fọ́n káà kiri, orílẹ̀-èdè Àlàáfíà Ẹ̀yin ara mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdẹwo ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀ Nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdẹwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣisẹ́ sùúrù Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò se aláìní ohunkóhun Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kì í sì ka àlébù sí a ó sì fi fún un Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá bèèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá Nítorí ẹni tí ó ń sé iyè méjì dàbí ìgbì omi òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé, òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́wọ́ Olúwa Ó jẹ ènìyàn oníyèméjì aláìllèdúró ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo Ṣùgbọ́n jẹ́ kí arákùnrin tí ó ń ṣe onírẹ̀lẹ̀ máa ṣògo ní ipò gíga Àti ọlọ́rọ̀, ní ìrẹ̀sílẹ̀, nítorí bí ìtànná koríko ni yóò kọjá lọ Nítorí oòrùn là ti òun ti ooru mímú ó sì gbẹ́ koríko, ìtànná rẹ̀ sì rẹ̀ dànú, ẹwà ojú rẹ̀ sì parun bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣègbé ní ọ̀nà rẹ̀ Ìbùkún ni fún ọkùnrin tí ó fi ọkàn rán ìdẹwò nítorí nígbà tí ó bá yege, yóò gba adé ìyè, tí Olúwa ti ṣèlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ Kí ẹnikẹ́ni tí a dẹwò kí ó má ṣe wí pé, Láti ọwọ́ Ọlọ́run ni a ti dán mi wò Nítorí a kò lè fi búburú dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnìkẹ́ni wò Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni a ń dánwò nígbà tí a bá fi ọwọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ fà á lọ tí a sì tàn án jẹ Ǹjẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nígbà tí ó bá lóyún a bí ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹ̀ṣẹ̀ náà nígbà tí ó bá dàgbà tán a bí ikú Kí a má ṣe tàn yín jẹ, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá Kí ẹmọ èyí, ẹ̀yin ara mi olùfẹ́ jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn kí ó si lọ́ra láti bínú Nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́ Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburútí ó gbilẹ̀ yíka, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là Ẹ maa kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rà náà lásán, kí ẹ má baà tipa èyí tan ara yín jẹ́ Ẹ ṣse ohun tí ó sọ Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú díńgí Nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti sàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójú kan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀ Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń sin Ọlọ́run nígbà tí kò kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ó ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsìn rẹ̀ sì jẹ́ asán Ìsìn mímọ́ àti aláìléèérí níwájú Ọlọ́run àti baba ni èyí, láti máa bojú tó àwọn aláìní-baba àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara rẹ̀ mọ́ láì lábàwọ́n kúrò nínú ayé Ojúṣàájú Jẹ́ Èèwò Ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ nínú ògo Olúwa wá Jésù Kírísítì, ẹ máa ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni Nítorí bí ọkùnrin kan bá wá sí ìpéjọpọ̀ yín, pẹ̀lú òrùka wúrà àti aṣọ dáradára, tí talákà kan sì wá pẹ̀lú nínú aṣọ èérí Tí ẹ̀yin sì bu ọla fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára tí ẹ sì wí fún talákà náà pé, Ìwọ dúró níbẹ̀ tàbí jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi Ẹ̀yin kò ha ń dá ara yín sí méjì nínú ara yín, ẹ̀yin kò sì di onídàájọ́ tí ó ní èrò búburú bí Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn talákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu talákà kù Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n ẹ̀yin lójú bí wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́ Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń mú olú òfin nì ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́, èyí tí ó wí pé, Ìwọ fẹ́ ẹni kejì rẹ bí ara rẹ, ẹ̀yin ń ṣe dáradára Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń ṣe ojúsáájú ènìyàn, ẹ̀yin ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ń dá yín lẹ́bi nípa òfin bí arúfin Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, tí ó sì rú ọ̀kan, ó jẹ̀bi rírú gbogbo rẹ̀ Nítorí ẹni tí ó wí pé, Má ṣe ṣe panṣágà, òun ni ó sì wí pé, Má ṣe pànìyàn Ǹjẹ́ bí ìwọ kò ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n tí ìwọ pànìyàn, ìwọ jásí arúfin Ẹ máa sọ̀rọ̀, ẹ sì máa hùwà, bí àwọn tí a ó fi òfin òmìnira dá lẹ́jọ́ Nítorí ẹni tí kò ṣàánú, ni a ó ṣe ìdájọ́ fún láìsí àánú àánú ń ṣògo lórí ìdájọ́ Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́ Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní àìní aṣọ, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́, Tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó, ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn èrè kí ni ó jẹ́ Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni lè wí pé, Ìwọ ní ìgbàgbọ́, èmi sì ní iṣẹ́ Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí ní àìsí iṣẹ́, èmi ó sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ rere mi Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wá rìrì Ṣùgbọ́n, ìwọ aláìmòye ènìyàn, ìwọ ha fẹ́ ní ìdánilójú pé, ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ rere asán ni Kí ha í ṣe nípa iṣẹ́ ni a dá Ábúrámù baba wa láre, nígbà tí ó fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ lórí pẹpẹ Ìwọ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ bá iṣẹ́ rìn, àti pé nípa iṣẹ́ rere ni a sọ ìgbàgbọ́ di pípé Ìwé mímọ́ sì ṣẹ́ tí ó wí pé, Ábúrámù gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un, a sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Ǹjẹ́ ẹ̀yin rí i pé nípa iṣẹ́ rere ni à ń dá ènìyàn láre, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú kí a dá Ráhábù panṣágà láre nípa iṣẹ́ bí, nígbà tí ó gba àwọn amí, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn Nítorí bí ara ní àìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú Kíkó Ahọ́n Ní Ìjánu Ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí púpọ̀ nínú yín jẹ́ olùkọ́, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé àwa ni yóò jẹ̀bi jù Nitorí nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣe àṣìse Bí ẹni kan kò bá sì sì ṣe nínú ọ̀rọ̀, òun náà ni ẹni pípé, òun ni ó sì le kó gbogbo ara ní ìjánu Bí a bá sì fi ìjánu bọ ẹṣin lẹ́nu, kí wọn kí ó le gbọ́ tiwa, gbogbo ara wọn ni àwa sì ń tì kiri pẹ̀lú Kíyèsí i, àwọn ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀ Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kéreré, ó sì ń fọhùn ohùn ńlá Wo igi ńlá tí iná kékeré ń sun jóna! Iná sì ni ahọ́n, ayé ẹ̀ṣẹ̀ sì ni ní àárin àwọn ẹ̀yà-ara wa, ní ahọ́n ti ń bá gbogbo ara jẹ́, tí yóò sì ti iná bọ ipa ayé wa ọ̀run àpáàdì a sì tiná bọ òun náà Nítorí olúkúlùkù ẹ̀dá ẹranko, àti ti ẹyẹ, àti ti ejò, àti ti ohun tí ó ń bẹ ní òkun, ni à ń tù lójú, tí a sì ti tù lójú láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wá Ṣùgbọ́n ahọ́n ni ẹnikẹ́ni kò le tù lójú ohun búburú aláìgbọ́ràn ni, ó kún fún oró ikú tíí pani Òun ni àwa fi ń yin Olúwa àti Baba, òun ni a sì fi ń bú ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run Láti ẹnu kan náà ni ìyìn àti èébú ti ń jáde Ẹ̀yin ará mi, nǹkan wọ̀nyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀ Orísun odò kan a ha máa sun omi dídará àti omi títẹ́jáde láti ojúsun kan náà bí Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ha le so èso ólífì bí Tàbí àjàrà ha lè so èso ọ̀pọ̀tọ́ Bẹ́ẹ̀ ni orísun kan kò le sun omíró àti omi tútù Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́ Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsáájú, a sì máa sọ òtítọ́ Àwọn tí ó ń ṣíṣẹ́ àlàáfíà a sì máa gbin èso àlàáfíà ní àlàáfíà Ìyọ̀ọ̀ǹda Ara Ẹni Fún Ọlọ́run Níbo ni ogun ti wá, níbo ni ìjà sì ti wá láàrin yín Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín ha kọ́ ni tí ó ń jagun nínú àwọn ẹ̀yà-ara yín bí Ẹ̀yin ń fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ẹ kò sì ní ẹ̀yin ń pànìyàn, ẹ sì ń ṣe ìlara, ẹ kò sì le ní ẹ̀yin ń jà, ẹ̀yin sì ń jagun ẹ kò ní, nítorí tí ẹ̀yin kò béèrè Ẹ̀yin béèrè, ẹ kò sì rí gbà, nítorí tí ẹ̀yin sì béèrè, kí ẹ̀yin kí ó lè lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín Ẹ̀yin panṣágà ọkùnrin, àti panságà obìnrin, ẹ kò mọ̀ pé ìbárẹ́ ayé ìṣọ̀tá Ọlọ́run ni Nítorí náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọ̀ta Ọlọ́run Ẹ̀yin ṣe bí ìwé mímọ́ sọ lásán pé, Ẹ̀mí tí ó fi sínú wa ń jowú gidigidi lórí wa Ṣùgbọ́n ó fún ni ní oore-ọ̀fẹ́ sí i Nítorí náà ni ìwé mímọ́ ṣe wí pé, Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga, ṣùgbọ́n ó fi ore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn Nítorí náà, ẹ tẹrí ba fún Ọlọ́run Ẹ kọ ojú ìjà sí èṣù, òun ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, òun ó sì sún mọ́ yín Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyèméjì Ẹ banújẹ́, ẹ sọ̀fọ̀, kí ẹ sì hu fún ẹkún Ẹ jẹ́ kí ẹ̀rín yín kí ó di ọ̀fọ̀, àti ayọ̀ yín kí ó di ìbànújẹ́ Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, òun ó sì gbé yín ga Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́ ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́ Aṣòfin àti onídàájọ́ kan ṣoṣo ní ó ń bẹ, àní ẹni tí ó lè gbà là tí ó sì le parun, Ṣùgbọ́n ta ni ìwọ tí ó ń dá ẹni kejì rẹ lẹ́jọ́ Ẹ wá nísinsìn yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la Kí ni ẹ̀mí yín Ìkuuku sáà ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ Èyí tí ẹ̀ bá fi wí pé, Bí Olúwa bá fẹ́, àwa yóò wà láàyè, àwa ó sì ṣe èyí tàbí èyí i nì Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, ẹ̀yin ń gbéraga nínú ìfọ́nnu yín, gbogbo irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀, ibi ni Nítorí náà ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un Ìkìlọ̀ Fún Àwọn Aninilára Ọlọ́rọ̀ Ẹ wá nísinsìn yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùn réré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín Góòlù òun sílífà yín díbàjẹ́ ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran ara yín bí iná Ẹ̀yin tí kó ìsúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn Kíyè sí i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa Ẹ̀yin ti dá ẹ̀bi fún olódodo, ẹ sì ti pa á òun kò kọ ojú ijà sí yín Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadàwá Olúwa Kíyèsí i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù ẹ fi ọkàn yín balẹ̀ nítorí ìpadàwá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀ Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má baà dá a yín lẹ́bi kíyè síi, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù Sáà wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fara dà ìyà sí ẹni ìbùkún Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jóòbù, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú Ṣùgbọ́n ju ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ má ṣe búra, ìbáà ṣe ìfi ọ̀run búra, tàbí ilẹ̀, tàbí ìbúra-kíbùúra mìíràn Ṣùgbọ́n jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ẹ má baà bọ́ sínú ẹ̀bi Inú ẹnikẹ́ni ha bàjẹ́ nínú yín bí Jẹ́ kí ó gbàdúrà Inú ẹnikẹ́ni ha dùn Jẹ́ kí ó kọrin mímọ́ Ẹnikẹ́ni ṣe àìsàn nínú yín bí Kí ó pe àwọn àgbà ìjọ, kí wọ́n sì gbàdúrà sórí rẹ̀, kí wọn fi òróró kùn ún ní orúkọ Olúwa Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì gba aláìsàń náà là, Olúwa yóò sì gbé e dìde bí ó bá sì ṣe pé ó ti dẹ́sẹ̀, a ó dárí jì í Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, kí a lè mú yín láradá Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń se ní agbára púpọ̀ Ènìyàn onírúurú ìwà bí àwa ni Èlíjà, ó gbàdúrà gidigidi pé kí òjò kí ó má ṣe rọ̀, òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà Ó sì tún gbàdúrà, ọ̀run sì tún rọ̀jò, ilẹ̀ sì so èso rẹ̀ jáde Ará, bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá sìnà kúrò nińu òtítọ́, tí ẹni kan sì yí i padà Jẹ́ kí ó mọ̀ pé, ẹni tí ó bá yí ẹlẹ́sẹ̀ kan padà kúrò nínú ìsìnà rẹ̀, yóò gba ọkàn kan là kúrò lọ́wọ́ ikú, yóò sì bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Ísírẹ́lì Bá Àwọn Ará Kénánì Tó Kù jagun Lẹ́yìn ikú Jóṣúà, ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé Èwo nínú ẹ̀yà wa ni yóò kọ́kọ́ gòkè lọ bá àwọn ará Kénánì jagun fún wa Olúwa sì dáhùn pé, Júdà ni yóò lọ nítorí pé èmi ti fi ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́ Nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Júdà béèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣíméónì arákùrin wọn pé, Ẹ wá bá wa gòkè lọ sí ilẹ̀ tí a ti fi fún wa, láti bá àwọn ará Kénánì jà kí a sì lé wọn kúrò, àwa pẹ̀lú yóò sì bá a yín lọ sí ilẹ̀ tiyín bákan náà láti ràn yín lọ́wọ́ Àwọn ọmọ ogun Síméónì sì bá àwọn ọmọ ogun Júdà lọ Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Júdà sì kọ lu àwọn ọmọ Kénánì, Olúwa ran àwọn Júdà lọ́wọ́, ó sì fi àwọn ará Kénánì àti àwọn ará Párísì lé wọn lọ́wọ́, àwọn Júdà sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ní Béṣékì nínú àwọn ọ̀ta wọn Ní Béṣékì ni wọ́n ti rí Adoni-Bésékì , wọ́n sì bá a jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ará Kénánì àti Párísì Ọba Adoni-Bésékì sá àṣálà, ṣùgbọ́n ogun Ísírẹ́lì lépa rẹ̀ wọ́n sì bá a, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ Nígbà náà ni ó wí pé, àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń sa ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi Báyìí Olúwa ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn, wọ́n sì mú un wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kú sí bẹ̀ Àwọn ológun Júdà sì ṣẹ́gun Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kénánì tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní Gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀ oòrùn Júdà jagun Ogun Júdà sì tún sígun tọ ará Kénánì tí ń gbé Hébírónì ó sì sẹ́gun Ṣẹ́ṣáì-Áhímánì àti Táímà Lẹ́yìn èyí wọ́n tẹ̀ṣíwájú láti bá àwọn tí ń gbé Débírì jagun Kélẹ́bù sì wí pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́ ṣíwájú ogun tí Kíríátì-Ṣáférì tí ó sì Ṣẹ́gun rẹ̀ ni èmi ó fún ní ọmọbìnrin mi Ákíṣà gẹ́gẹ́ bí aya Ótíníẹ́lì ọmọ Kénásì àbúrò Kélẹ́bù ṣíwájú, wọ́n sì kọ lu ìlú náà, ó sì fún un ní Ákíṣà gẹ́gẹ́ bí aya Ní ọjọ́ kan nígbà tí Ákíṣà wá sí ọ̀dọ̀ Ótíníélì, ó rọ ọkọ rẹ̀ láti tọrọ oko lọ́wọ́ Kélẹ́bù baba rẹ̀ Nígbà tí Ákíṣà ti sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ Kélẹ́bù bi í léèrè pé, Kí ni o ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ Ákíṣà sì dáhùn pé, Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojú rere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní Gúúsù fún mi ní ìṣun omi náà pẹ̀lú Kélẹ́bù sì fún un ní ìṣun òkè àti ìṣun ìṣàlẹ̀ Àwọn ìran Kénì tí wọ́n jẹ́ àna Móṣè bá àwọn Júdà gòkè ní gúṣù nítorí Árádì àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì sì jùmọ̀ ń gbé pọ̀ láti ìgbà náà Ó sì ṣe, àwọn ológun Júdà tẹ̀lé àwọn ológun Ṣíméónì arákùnrin wọn, wọ́n sì lọ bá àwọn ará Kénánì tí ń gbé Ṣéfátì jagun, wọ́n sì run ìlú náà pátapáta, ní báyìí à ò pe ìlú náà ní Hómà Àwọn ogun Júdà sì ṣẹ́gun Gásà àti àwọn agbègbè rẹ̀, Ásíkélénì àti Ékírónì pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó yí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ká Olúwa sì wà pẹ̀lú ẹ̀yà Júdà, wọ́n gba ilẹ̀ òkè ṣùgbọ́n wọn kò le lé àwọn ènìyàn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí wọ́n ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin Gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti ṣèlérí, wọ́n fún Kélẹ́bù ní Hébírónì ó sì lé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kúrò àwọn náà ni ìran àwọn ọmọ Ánákì mẹ́ta Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni wọn kò le lé àwọn Jébúsì tí wọ́n ń gbé Jérúsálẹ́mù nítorí náà wọ́n ń gbé àárin àwọn Ísírẹ́lì títí di òní Àwọn ẹ̀yà Jóṣẹ́fù sì bá Bẹ́tẹ́lì jagun, Olúwa ṣíwájú pẹ̀lú wọn Nígbà tí ẹ̀yà Jóṣẹ́fù rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Bẹ́tẹ́lì wò Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, Fi ọ̀nà àti wọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mìí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ Ó sì fi ọ̀nà ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ si Ọkùnrin náà sí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hítì, ó sì tẹ ìlú kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lúsì èyí sì ni orúkọ rẹ̀ títí di òní Àwọn ẹ̀yà Mánásè sì kùnà láti lé àwọn tí ń gbé Bẹti-Sésínì àti àwọn ìlú agbègbè wọn jáde, tàbí àwọn ará Tánákì àti àwọn ìgbéríko rẹ̀, tàbí àwọn olùgbé Mégídò àti àwọn ìgbéríko tí ó yí i ká torí pé àwọn ará Kénánì ti pinnu láti máa gbé ìlú náà Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di alágbára, wọ́n mú àwọn ará Kénánì sìn bí i ẹrú, ṣùgbọ́n wọn kò fi agbára lé wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà Éfúráímù náà kò lé àwọn ará Kénánì tí ó ń gbé Géṣérì jáde, ṣùgbọ́n àwọn ará Kénánì sì ń gbé láàrin àwọn ẹ̀yà Éfúráímù Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹ̀yà Ṣébúlúnì náà kò lé àwọn ará Kítírónì tàbí àwọn ará Nẹ́hálólì ṣùgbọ́n wọ́n sọ wọ́n di ẹrú Wọ́n sì ń sin àwọn ará Ṣébúlúnì Bẹ́ẹ̀ ni Áṣérì kò lé àwọn tí ń gbé ní Ákò àti Áhálábì àti Ákísíbì àti Hélíbáhà àti Háfékì àti Réhóbù Ṣùgbọ́n nítorí àwọn Áṣérì ń gbé láàrin àwọn ará Kénánì tí wọ́n ni ilẹ̀ náà Àwọn ẹ̀yà Náfítalì pẹ̀lú kò lé àwọn ará Bétì-Ṣémésì àti Bẹti-Ánátì jáde ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Náfítanì náà ń gbé àárin àwọn ará Kénánì tí ó ti ní ilẹ̀ náà rí, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé Bẹti-Ṣéméṣì àti Bẹti-Ánátì ń sìn ìsìn tipátipá Àwọn ará Ámórì fi agbára dá àwọn ẹ̀yà Dánì dúró sí àwọn ìlú orí òkè, wọn kò sì jẹ́ kí wọn sọ̀kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Àwọn ará Ámórì ti pinnu láti dúró lórí òkè Hérésì àti òkè Áíjálónì àti ti Ṣáíbímù, ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yà Jósẹ́fù di alágbára wọ́n borí Ámórì wọ́n sì mú wọn sìn Ààlà àwọn ará Ámórì sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgòkè Ákírábímù kọjá lọ sí Ṣélà àti síwájú sí i Tólà Lẹ́yìn ikú Ábímélékì, ọkùnrin kan láti ẹ̀yà Ísákárì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tólà ọmọ Púà, ọmọ Dódò, dìde láti gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ Ní Sámírì tí ó wà ní òkè Éfúráímù ni ó gbé Ó ṣe àkóso Ísírẹ́lì ní ọdún mẹ́talélógún Nígbà tí ó kú wọ́n sìn ín sí Sámírì Jáírì ti ẹ̀yà Gílíádì ni ó dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó ṣàkóso Ísirẹ́lì ní ọdún méjìlélógún Àwọn ọgbọ̀n ọmọ tí ó ní gún ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Wọ́n ṣe àkóso ọgbọ̀n ìlú ní Gílíádì, tí a pe orúkọ wọn ní Háfótì Jáírì títí di òní Nígbà tí Jáírì kú wọ́n sin ín sí Kámónì Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún ṣe ohun tí ó burú lójú Olúwa Wọ́n sin Báálì àti Áṣítórétù àti àwọn òrìṣà Árámù, òrìṣà Ṣídónì, òrìṣà Móábù, òrìṣà àwọn ará Ámónì àti òrìṣà àwọn ará Fílístínì Nítorí àwọn ará Ísírẹ́lì kọ Olúwa sílẹ̀ tí wọn kò sì sìn-ín mọ́, ó bínú sí wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ará Fílístínì àti Ámónì láti jẹ ẹ́ ní ìyà Ní ọdún náà, wọ́n tú wọn ká wọ́n sì pọ́n wọn lójú Fún ọdún méjìdínlógún ni wọ́n fi ni gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́li tí ó wà ní ìlà oòrùn odò Jọ́dánì ní ilẹ̀ àwọn ará Ámórì lára Àwọn ará Ámónì sì la odò Jọ́dánì kọjá láti bá Júdà, Bẹ́ńjámínì àti àwọn ará ilé Éfúráímù jagun Ísírẹ́lì sì dojú kọ ìpọ́njú tó lágbára Nígbà tí èyí ti ṣẹlẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Olúwa wí pé, Àwa ti ṣẹ̀ sí ọ, nítorí pé àwa ti kọ Ọlọ́run wa sílẹ̀, àwa sì ń sin Báálì Olúwa sì dáhùn pé, Ǹjẹ́ nígbà tí àwọn ará Éjíbítì, Ámórì, Ámónì, Fílístínì, àwọn ará Sídónì, Ámélékì pẹ̀lú Móánì ni yín lára, tí ẹ sì ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, ǹjẹ́ èmi kò gbà yín sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ wọn Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kọ̀ mí sílẹ̀ láti sin àwọn ọlọ́run mìíràn, torí ìdí èyí, èmi kì yóò sì tún gbà yín mọ́ Ẹ lọ kí ẹ sì ké pe àwọn òrìṣà tí ẹ̀yin ti yàn fún ara yín Jẹ́ kí wọn gbà yín sílẹ̀ ní àsìkò ìpọ́njú yín! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dá Olúwa lóhùn pé, Àwá ti ṣẹ̀, ṣe ohun tí ó bá fẹ́ pẹ̀lú wa, ṣùgbọ́n, jọ̀wọ́ gbà wá sílẹ̀ ná ní àsìkò yìí Nígbà náà ni wọ́n kó gbogbo ọlọ́run àjèjì tí ó wà láàárin wọn kúrò wọ́n sì sin Olúwa nìkan, ọkàn rẹ̀ kò sì le gbàgbé ìrora Ísírẹ́lì mọ́ Nígbà tí àwọn ará Ámónì kógun jọ ní Gílíádì láti bá Ísírẹ́lì jà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbárajọpọ̀ wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Mísípà Àwọn ìjòyè aṣíwájú àwọn ará Gílíádì wí fún ará wọn pé, Ẹnikẹ́ni tí yóò kọ́ sígun si àwọn ará Ámónì ni yóò jẹ́ orí fún gbogbo àwọn tí ń gbé ní Gílíádì Jẹ́fítà ará Gílíádì jẹ́ akọni jagunjagun Gílíádì ni baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ jẹ́ aṣẹ́wó Ìyàwó Gílíádì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un, nígbà tí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí dàgbà, wọ́n rán Jẹ́fità jáde kúrò nílé, wọ́n wí pé, Ìwọ kì yóò ní ogún kankan ní ìdílé wa, nítorí pé ìwọ jẹ́ ọmọ obìnrin mìíràn Jẹ́fità sì sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì pàgọ́ sí ilẹ̀ Tóbù, ó sì ń gbé níbẹ̀, níbẹ̀ ni àwọn ènìyàn kan ti ń tẹ ofìn lójú para pọ̀ láti máa tẹ̀lé e kiri Ní àsìkò kan, nígbà tí àwọn ará Ámónì dìde ogun sí àwọn Ísírẹ́lì, Àwọn ìjòyè aṣíwájú Gílíádì tọ Jẹ́fítà lọ láti pè é wá láti ilẹ̀ Tóbù Wọ́n wí fún Jẹ́fità wí pé, Wá kí o sì jẹ́ olórí ogun wa kí a lè kọjú ogun sí àwọn ará Ámónì Jẹ́fítà sì dáhùn pé, Ṣé kì í ṣe pé ẹ kóríra mi tí ẹ sì lé mi kúrò ní ilé baba mi Kí ló dé tí ẹ fi tọ̀ mí wá báyìí nígbà tí ẹ wà nínú wàhálà Àwọn ìjòyè àgbà Gílíádì dáhùn pé, Nítorí rẹ̀ ni àwa fi yípadà sí ọ báyìí tẹ̀lé wa, kí a lè dojú ìjà kọ àwọn ará Ámónì, ìwọ yóò sì jẹ olórí wa àti gbogbo àwa tí ń gbé ní Gílíádì Jẹ́fità dáhùn pé, Bí ẹ̀yin bá mú mi padà láti bá àwọn ará Ámónì jà àti tí Olúwa bá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ ṣe èmi yóò jẹ́ olórí yín nítòótọ́ Àwọn ìjòyè Gílíádì dáhùn pé, Àwa fi Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá wí Jẹ́fità sì tẹ̀lé àwọn olóyè Gílíádì lọ, àwọn ènìyàn náà sì fi ṣe olórí àti ọ̀gágun wọn Jẹ́fità sì tún sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ níwájú Olúwa ní Mísípà Jẹ́fítà sì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba àwọn ará Ámónì pé, Kí ni ẹ̀ṣùn tí o ní sí wa láti fi kàn wá tí ìwọ fi dojú ìjà kọ ilẹ̀ wa Ọba àwọn Ámónì dá àwọn oníṣẹ́ Jẹ́fità lóhùn pé, Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ti Éjíbítì wá Wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Ánónì dé Jábókù, àní dé Jọ́dánì, nítorí náà dá wọn padà lọ ní àlàáfíà àti ní pẹ̀lẹ́ kùtù Jẹ́fítà sì tún ránṣẹ́ padà sí ọba àwọn ará Ámónì ó sì wí fún un pé Báyìí ni Jẹ́fítà wí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gba ilẹ̀ Móábù tàbí ilẹ̀ àwọn ará Ámónì Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Éjíbítì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la ihà kọjá lọ sí ọ̀nà òkun pupa wọ́n sì lọ sí Kádésì Nígbà náà Ísírẹ́lì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba Édómù pé, Gbà fún wa láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá, ṣùgbọ́n ọba Édómù kò fetí sí wọn Wọ́n tún ránṣẹ́ sí ọba Móábù bákan náà òun náà kọ̀ Nítorí náà Ísírẹ́lì dúró sí Kádésì Wọ́n rin ihà kọjá, wọ́n pẹ́ àwọn ilẹ̀ Édómù àti ti Móábù sílẹ̀, nígbà tí wọ́n gba apá ìlà oòrùn Móábù, wọ́n sì tẹ̀dó sí apá kejì Ánónì Wọn kò wọ ilẹ̀ Móábù, nítorí pé ààlà rẹ̀ ni Ánónì wà Nígbà náà ni Ísírẹ́lì rán àwọn oníṣẹ́ sí Síhónì ọba àwọn ará Ámórì, ẹni tí ń ṣe àkóso ní Hésíbónì, wọ́n sì wí fún un pé, Jẹ́ kí a la ilẹ̀ rẹ kọja lọ sí ibùgbé wa Ṣùgbọ́n Síhónì kò gba Ísírẹ́lì gbọ́ láti jẹ́ kí ó kọjá Ó kó gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ, ó sì tẹ̀dó sí Jáhásì láti bá Ísírẹ́lì jagun Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì fi Síónì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Ámórì tí wọ́n ń gbé ní agbégbé náà, wọ́n gbà gbogbo agbégbé àwọn ará Ámórì tí ó fi dé Jábókù, àti láti aṣálẹ̀ dé Jọ́dánì Wàyí o, nígbà tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti lé àwọn ará Ámórì kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì, ẹ̀tọ́ wo ni ẹ ní láti gba ilẹ̀ náà Ǹjẹ́ ìwọ kì yóò ha gba èyí tí Kémọ́sì òrìṣà rẹ fí fún ọ Bákan náà àwa yóò gba èyíkéyìí tí Olúwa Ọlọ́run wa fi fún wa Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn jú Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù lọ Ǹjẹ́ òun ha ṣe gbólóhùn aṣọ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì bí Tàbí òun dojú ìjà kọ wọ́n rí bí Fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún ni Ísírẹ́lì fi ṣe àtìpó ní Hésíbónì, Áróérì àti àwọn ìgbéríko àti àwọn ìlú tí ó yí Ánónì ká Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà Èmi kọ́ ni ó ṣẹ̀ ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ ni ó ṣẹ̀ mí nípa kíkógun tọ̀ mí wá Jẹ́ kí Olúwa olùdájọ́, ṣe ìdájọ́ lónìí láàárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ará Ámónì Ṣùgbọ́n ọba àwọn Ámónì kò fetí sí iṣẹ́ tí Jẹ́fítà rán síi Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jẹ́fítà òun sì la Gílíádì àti Mánásè kọjá Ó la Mísípà àti Gílíádì kọja láti ibẹ̀, ó tẹ̀ṣíwájú láti bá àwọn ará Ámónì jà Jẹ́fítà sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa pé, Bí ìwọ bá fi àwọn ará Ámónì lé mi lọ́wọ́, Ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde láti ẹnu ọ̀nà mi láti wá pàdé mi, nígbà tí èmi bá ń padà bọ̀ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọmọ Ámónì yóò jẹ́ ti Olúwa , èmi yóò sì fi rúbọ bí ọrẹ ẹbọ ṣíṣun Jẹ́fítà sì jáde lọ láti bá àwọn ará Ámónì jagun, Olúwa sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́ Òun sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa wọ́n ní àpa tán láti Áróérì títí dé agbègbè Mínítì, ó jẹ́ ogún ìlú, títí dé Abeli-Kérámímù Báyìí ni Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun àwọn ará Ámónì Nígbà tí Jẹ́fítà padà sí ilé rẹ̀ ní Mísípà, wò ó, ọmọ rẹ̀ obìnrin ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀ pẹ̀lú taboríìnì àti ijó Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó ní kò ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn yàtọ̀ sí òun nìkan Ní ìgbà tí ó rí i ó fa aṣọ rẹ̀ ya ní ìbànújẹ́, ó sì ké wí pé, Háà! Ọ̀dọ́mọbìnrin mi, ìwọ fún mi ní ìbànújẹ́ ọkàn ìwọ sì rẹ̀ mí sílẹ̀ gidigidi, nítorí pé èmi ti ya ẹnu mi sí Olúwa ní ẹ̀jẹ́, èmi kò sì le ṣẹ́ ẹ̀jẹ́ mi Ọmọ náà sì dáhùn pé, Baba mi bí ìwọ bá ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa , ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, ní báyìí tí Olúwa ti gba ẹ̀ṣan fún ọ lára àwọn ọ̀ta rẹ, àwọn ará Ámónì Ṣùgbọ́n yọ̀ǹda ìbéèrè kan yìí fún mi, gbà mí láàyè oṣù méjì láti rìn ká orí àwọn òkè, kí n ṣunkún pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi torí mo jẹ́ wúndíá tí n kò sì ní lè ṣe ìgbéyàwó Jẹ́fítà dá lóhùn pé, Ìwọ lè lọ Ó sì gbà á láàyè láti lọ fún oṣù méjì Òun àti àwọn ọmọbìnrin yóòkù lọ sí orí àwọn òkè, wọ́n ṣunkún nítorí pé kì yóò lè ṣe ìgbéyàwó Lẹ́yìn oṣù méjì náà, ó padà tọ baba rẹ̀ wá òun sì ṣe sí i bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti jẹ́ Ọmọ náà sì jẹ́ wúndíá tí kò mọ ọkùnrin rí Èyí sì bẹ̀rẹ̀ àṣà kan ní Ísírẹ́lì wí pé ní ọjọ́ mẹ́rin láàrin ọdún àwọn obìnrin Ísírẹ́lì a máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti ṣe ìrántí ọmọbìnrin Jẹ́fítà ti Gílíádì Jẹ́fítà Àti Éfúráímù Àwọn ọkùnrin Éfúráímù pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí Sáfónì, wọ́n sì bi Jẹ́fítà pé, Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ámónì jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ Àwa yóò ṣun ilé rẹ mọ́ ọ lórí Jẹ́fítà dáhùn pé, Èmi àti àwọn ènìyàn ní ìyọnu ńlá pẹ̀lú àwọn ará Ámórì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pè yín, ẹ̀yin kò gbà mí sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn Nígbà tí mo ríi pé ẹ̀yin kò ṣetán láti ṣe ìrànlọ́wọ́, mo fi ẹ̀mi mi wéwu Mó sì gòkè lọ láti bá àwọn ará Ámónì jà, Olúwa sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn, Èéṣe báyìí tí ẹ fi dìde wá lónìí láti bá mi jà Jẹ́fítà sì pe àwọn ọkùnrin Gílíádì, wọ́n sì bá àwọn ará Éfúráímù jà Àwọn ará Gílíádì run wọ́n nítorí pé àwọn ará Éfúráímù ti ṣọ tẹ́lẹ̀ pé, Ẹ̀yin ará Gílíádì jẹ́ àṣáwọ̀ àwọn ará Éfúráímù àti ti Mànásè Àwọn ará Gílíádì gba àbáwọdò Jọ́dánì tí wọ́n máa gbà lọ sí Éfúráímù, nígbàkígbà tí àwọn ará Éfúráímù bá wí pé, Jẹ́ kí ń sá lọ sí òkè, lọ́hùn ún àwọn ará Gílíádì yóò bi í pé, Ṣé ará Éfúráímù ni ìwọ ń ṣe Tí ó bá wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n ó wí fún un pé, Ó dá à wí pé Ṣhíbólétì   Tí ó bá ní, Síbólé, tì torí pé kò ní mọ̀ọ́ pé dáadáa, wọ́n á mú-un wọn, a sì pa á ni àbáwọdò Jọ́dánì Àwọn ará Éfúráímù tí wọn pa ní àkókò yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìléní-ogójì ọkùnrin Jẹ́fítà ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní ọdún mẹ́fà Lẹ́yìn náà Jẹ́fítà ará Gílíádì kú, wọ́n sì sin ín sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú Gílíádì Lẹ́yìn Jẹ́fítà, Íbísánì ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ó ní ọgbọ̀n ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọbìnrin fún àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n àwọn ọmọbìnrin fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lára àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀ Ó ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún méje Lẹ́yìn náà ni Íbísánì kú, wọ́n sì sin ín sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Lẹ́yìn rẹ̀, Élónì ti ẹ̀yà Ṣébúlúnì ṣe àkóso Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́wàá Élónì sì kú, wọ́n sì sin ín sí Áíjálónì ní ilẹ̀ Ṣébúlúnì Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ábídónì ọmọ Hiélì tí Pírátónì n ṣe àkóso Ísírẹ́lì Òun ní ogójì ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọ ọmọ àwọn tí ó ń gun àádọ́rin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ó ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní ọdún mẹ́jọ Ábídónì ọmọ Híélì sì kú, wọ́n sin ín sí Pírátónì ní ilé Éfúráímù ní ìlú òkè àwọn ará Ámálékì Ìbí Sámúsònì Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa , Olúwa sì fi wọ́n lé àwọn ará Fílístínì lọ́wọ́ fún ogójì ọdún Ọkùnrin ará Sórà kan wà, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Mánóà láti ẹ̀yà Dánì Aya rẹ̀ yàgàn kò sì bímọ Ańgẹ́lì Olúwa fara han obìnrin náà, ó sì wí fún un pé, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yàgàn, ìwọ kò sì tíì bímọ, ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan Báyìí rí i dájúdájú pé ìwọ kò mu wáìnì tàbí ọtí líle kankan àti pé ìwọ kò jẹ ohun aláìmọ́ kankan, nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan Má se fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Fílístínì Nígbà náà ni obìnrin náà tọ ọkọ rẹ̀ lọ, o sì sọ fún un wí pé, Èniyàn Ọlọ́run kan tọ̀ mí wá Ó jọ ańgẹ́lì Ọlọ́run, ó bà ènìyàn lẹ́rù gidigidi Èmi kò béèrè ibi tí ó ti wá, òun náà kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wí pé, Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, fún ìdí èyí, má ṣe mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má se jẹ ohunkóhun tí í ṣe aláìmọ́, nítorí pé Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀   Nígbà náà ni Mánóà gbàdúrà sí Olúwa wí pé, Háà Olúwa , èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà Ọlọ́run fetí sí ohùn Mánóà, ańgẹ́lì Ọlọ́run náà tún padà tọ obìnrin náà wá nígbà tí ó wà ní oko Ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ Mánóà kò sí ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ Nítorí náà ni obìnrin náà ṣe yára lọ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, Ọkùnrin tí ó fara hàn mí ní ọjọ́sí ti tún padà wá Mánóà yára dìde, ó sì tẹ̀lé aya rẹ̀, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin náà ó ní, Ǹjẹ́ ìwọ ni o bá obìnrin yìí sọ̀rọ̀ Ọkùnrin náà dáhùn pé Èmi ni Mánóà bi ọkùnrin náà pé, Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ kí ni yóò jẹ́ ìlànà fún ìgbé ayé àti iṣẹ́ ọmọ náà Ańgẹ́lì Olúwa náà dáhùn wí pé, Aya rẹ gbọdọ̀ ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ fún un kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti inú èṣo àjàrà jáde wá, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn tàbí jẹ ohunkóhun tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ Ó ní láti ṣe ohun gbogbo tí mo ti pa láṣẹ fún un Mánóà sọ fún ańgẹ́lì Olúwa náà pé, Jọ̀wọ́ dára dúró títí àwa yóò fi pèṣè ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan fún ọ Ańgẹ́lì Olúwa náà dá Mánóà lóhùn pé, Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, Èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹyin yóò pèṣè Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèṣè ọrẹ ẹbọ ṣíṣun, kí ẹ sì fi rúbọ sí Olúwa Mánóà sì béèrè lọ́wọ́ ańgẹ́lì Olúwa náà pé, Kí ni orúkọ rẹ, kí àwa bá à lè fi ọlá fún ọ nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ Ṣùgbọ́n ańgẹ́lì Olúwa náà dáhùn pé, Èéṣe tí ìwọ ń béèrè ọrúkọ mi Ìyanu ni, ó kọjá ìmọ̀ Lẹ́yìn náà ni Mánóà mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọkà, ó sì fi rúbọ lórí àpáta kan sí Olúwa Nígbà tí Mánóà àti ìyàwó dúró tí wọn ń wò Olúwa ṣe ohun ìyanu kan Bí ẹ̀là ahọ́n iná ti là jáde láti ibi pẹpẹ ìrúbọ náà sí ọ̀run, ańgẹ́lì Olúwa gòkè re ọ̀run láàárin ahọ́n iná náà Nígbà tí wọ́n rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Mánóà àti aya rẹ̀ wólẹ̀ wọ́n sì dojú bolẹ̀ Nígbà tí ańgẹ́lì Olúwa náà kò tún fi ara rẹ̀ han Mánóà àti aya rẹ̀ mọ́, Mánóà wá mọ̀ pé ańgẹ́lì Olúwa ni Mánóà sọ fún aya rẹ̀ pé, Dájúdájú àwa yóò kú nítorí àwa ti fi ojú rí Ọlọ́run Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, Bí Olúwa bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ọrẹ ṣísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa Obínrìn náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ṣáḿsónì Ọmọ náà dàgbà Olúwa sì bùkún un Ẹ̀mí Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nígbà tí ó wà ní Máháne-dánì ní agbede-méjì Sórà àti Ésítaólì Ìgbéyàwó Sámúsónì Nígbà kan Sámúsónì gòkè lọ sí Tímínà níbẹ̀ ni ó ti rí ọmọbìnrin Fílístínì kan Nígbà tí ó darí dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé, Mo rí obìnrin Fílístínì kan ní Tímínà báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárin àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàárin gbogbo àwọn ènìyàn wa Ṣé ó di túlàsì fún ọ láti lọ sí àárin àwọn Fílístínì aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó Ṣùgbọ́n Sámúsónì wí fún baba rẹ̀ pé, Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ síi púpọ̀ púpọ̀ Sámúsónì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Tímínà òun àti bàbá àti ìyá rẹ̀ Bí wọ́n ṣe ń súnmọ́ àwọn ọgbà àjàrà tí ó wà ní Tímínà, láìrò tẹ́lẹ̀, ọ̀dọ́ kìnnìún kan jáde síta tí ń ké ramúramù bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé e pẹ̀lú agbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fa kìnnìún náà ya pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lásán bí ẹní ya ọmọ ewúrẹ́, ṣùgbọ́n òun kò sọ ohun tí ó ṣe fún baba tàbí ìyá rẹ̀ Ó sì lọ bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, inú Sámúsónì sì yọ́ sí i Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, nígbà tí ó padà lọ láti gbé e níyàwó, ó yà lọ láti wo òkú kìnìún náà Inú rẹ̀ ni ó ti bá ọ̀pọ̀ ìṣù oyin àti oyin, ó fi ọwọ́ ha jáde, ó sì ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń lọ Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó fún wọn ní díẹ̀, àwọn náà sì jẹ, ṣùgbọ́n kò sọ fún wọn pé ara òkú kìnnìún ni òun ti rí oyin náà Baba rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti kí obìnrin náà Sámúsónì sì ṣe àṣè gẹ́gẹ́ bí àṣà ọkọ ìyàwó ní àkókò náà Nígbà tí ó fara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́ Sámúsónì sọ fún wọn pé, Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtúmọ̀ rẹ̀ láàárin ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àdìtú náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n ìpàrọ̀ aṣọ ìyàwó Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpàrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó Wọ́n dáhùn pé, Sọ àlọ́ rẹ fún wa jẹ́ kí a gbọ́ Ó dáhùn pé, Láti inú ọ̀jẹun ni ohun jíjẹ ti jáde wá láti inú alágbára ni ohun dídùn ti jáde wá Ṣùgbọ́n fún odidi ọjọ́ mẹ́ta ni wọn kò fi rí ìtúmọ̀ sí àlọ́ náà Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n wí fún ìyàwó Sámúsónì, pé, Tan ọkọ rẹ kí ó lè ṣe àlàyé àlọ́ náà fún wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò sun ìwọ àti ìdílé baba rẹ̀ ní iná Tàbí ṣe o pè wá sí ibi àsè yìí láti sọ wá di òtòsì tàbí kó wa lẹ́rú ni Nígbà náà ni ìyàwó Sámúsónì ṣubú lé e láyà, ó sì sunkún ní iwájú rẹ̀ pé, O kórìíra mi! o kò sì ní ìfẹ́ mi nítòótọ́, o pàlọ́ fún àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi Èmi kò tí ì ṣe àlàyé rẹ̀ fún baba àti ìyá mi, báwo ni èmi ó ṣe sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sunkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́ Òun náà sì sọ ìtúmọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ Kí ó tó di àṣálẹ́ ọjọ́ keje àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé, Kí ni ó dùn ju oyin lọ Kí ni ó sì lágbára ju kìnìún lọ Sámúsónì dá wọn lóhùn pé, Bí kì í bá ṣe pé ẹ fi ọ̀dọ́ màlúù mi kọ ilẹ̀, ẹ̀yin kò bá tí mọ ìtumọ̀ sí àlọ́ mi Lẹ́yìn èyí, ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára Ó lọ sí Ásíkélónì, ó pa ọgbọ̀n nínú àwọn ọkùnrin wọn, ó gba àwọn ohun ìní wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wọn fún àwọn tí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà Ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú ríru Wọ́n sì fi ìyàwó Sámúsónì fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ rẹ̀ nígbà ìgbéyàwó rẹ̀ Ẹ̀san Sámúsónì Lára Àwọn Ará Fílístínì Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè jéró Sámúsónì mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan láti bẹ ìyàwó rẹ̀ wò Ó ní, Èmi yóò wọ yàrá ìyàwó mi lọ Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà á láàyè láti wọlé Baba ìyàwó dá a lóhùn pé, Ó dá mi lójú pé o kórìíra rẹ̀, torí náà mo ti fi fún ọ̀rẹ́ rẹ, ṣebí àbúrò rẹ̀ obìnrin kò ha lẹ́wà jù lọ Fẹ́ ẹ dípò rẹ̀ Sámúsónì dáhùn pé, Ní àkókò yìí tí mo bá ṣe àwọn Fílístínì ní ibi èmi yóò jẹ́ aláìjẹ̀bi Òun sì jáde lọ, ó mú ọ̀ọ́dúnrún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ó so ìrù wọn mọ́ ara wọn ní méjìméjì Ó mú ètùfù iná, ó so ó mọ́ àwọn ìrù tí ó so pọ̀ Ó fi iná ran àwọn ètúfù tí ó so náà, ó sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ sínú àwọn oko ọkà àwọn Fílístínì Ó jó àwọn pòpóòrò ọkà tí ó dúró àti àwọn tí a dì ní ìtí, ìtí, pẹ̀lú àwọn oko àjàrà àti ólífì Nígbà tí àwọn Fílístínì béèrè pé, Ta ni ó ṣe èyí Wọ́n dá wọn lóhùn pé, Sámúsónì ará Tímínà ni, nítorí o gba ìyàwó rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ Nítorí náà àwọn Fílístínì lọ wọ́n sì ṣun obìnrin náà àti baba rẹ̀ Sámúsónì sọ fún un pé, Nítorí pé ẹ̀yin ṣe èyí, èmi kò dẹṣẹ̀ títí èmi yóò fi gbẹ̀ṣan mi lára yín Ó kọ lù wọ́n pẹ̀lú ìbínú àti agbára ńlá, ó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn Lẹ́yìn náà ni ó lọ, ó sì dúró nínú ihò àpáta kan nínú àpáta Étamù Àwọn ará Fílístínì sì dìde ogun sí Júdà, wọ́n ti tan ara wọn ká sí agbégbé Léhì Àwọn ọkùnrin Júdà sì bèèrè pé, Èéṣe tí ẹ fi wá gbógun tì wá Ìdáhùn wọn ni pé, Awá láti mú Sámúsónì ní ìgbékùn, kí a ṣe sí i bí òun ti ṣe sí wa Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkùnrin láti Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ sí ihò àpáta nínú àpáta Étamù, wọ́n sì sọ fún Sámúsónì pé, Kò ti yé ọ pé àwọn Fílístínì ní ń ṣe alákóṣo lórí wa Kí ni o ṣe sí wa Òun sì dáhùn pé, Ohun tí wọ́n ṣe sí mi ni èmi náà ṣe sí wọn Wọ́n wí pé, Àwa wá láti dè ọ́, kí a sì fi ọ́ lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́ Sámúsónì wí pé, Ẹ búra fún mi pé, ẹ̀yin kì yóò fúnra yín pa mí Àwá gbà, ni ìdáhùn wọn Àwa yóò kàn dè ọ́, awa yóò sì fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́, àwa kì yóò pa ọ́ Wọ́n sì dé pẹ̀lú okùn túntún méjì, wọ́n sì mú u jáde wá láti ihò àpáta náà Bí ó ti sún mọ́ Léhì, àwọn Fílístínì ń pariwo bí wọ́n ṣe ń tò bọ̀ Ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára Àwọn okùn ọwọ́ rẹ̀ dàbí òwú tí ó jóná, ìdè ọwọ́ rẹ̀ já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ Nígbà tí ó rí egungun àgbọ̀n ìṣàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ túntún kan, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin Sámúsónì sì wí pé, Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan Mo sọ wọ́n di òkìtì kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan Mo ti pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin Nígbà tí ó dákẹ́ ọ̀rọ̀ ísọ, ó ju egungun àgbọ̀n ìṣàlẹ̀ náà nù, wọ́n sì pe ibẹ̀ ní Ramati-Léhì Nítorí tí òǹgbẹ gbẹ ẹ́ gidigidi, ó ké pe Olúwa , wí pé, Ìwọ ti fún ìránṣẹ́ ní ìṣẹ́gun tí ó tóbi yìí Ṣé èmi yóò ha kú pẹ̀lú òǹgbẹ, kí èmi sì ṣubú sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà ènìyàn Nígbà náà ni Ọlọ́run la kòtò ìṣun omi tí ó wà ní Léhì, omi sì tú jáde láti inú rẹ̀ Nígbà tí Sámúsónì mú mi tan, agbára rẹ̀ sì padà, ọkàn sì sọjí, fún ìdí èyí wọ́n pe ìṣun omi náà ni Ẹni Hákkò rẹ èyí tí ó sì wà ní Léhì di òní Sámúsónì ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ogún ọdún ní àkókò àwọn ará Fílístínì Sámúsónì Àti Dẹ̀lílà Ní ọjọ́ kan Sámúsónì lọ sí Gásà níbi tí ó ti rí obìnrin aṣẹ́wó kan Ó wọlé tọ̀ ọ́ láti ṣun ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òru ọjọ́ náà Àwọn ará Gásà sì gbọ́ wí pé, Sámúsónì wà níbí Wọ́n sì yí agbégbé náà ká, wọ́n ń ṣọ́ ọ ní gbogbo òru náà ní ẹnu bodè ìlú náà Wọn kò mira ní gbogbo òrú náà pé ní àfẹ̀mọ́júmọ́ àwa yóò pa á Ṣùgbọ́n Sámúsónì sùn níbẹ̀ di àárin ọ̀gànjọ́ Òun sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó fi ọwọ́ di àwọn ìlẹ̀kùn odi ìlú náà mú, pẹ̀lú òpó méjèèjì, ó sì fà wọ́n tu, pẹ̀lú ìdábú àti ohun gbogbo tí ó wà lára rẹ̀ Ó gbé wọn lé èjìká rẹ̀ òun sì gbé wọn lọ sí orí òkè tí ó kọjú sí Hébírónì Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó sì ní ìfẹ́ obìnrin kan ní àfonífojì Ṣórékì, orúkọ ẹni tí í ṣe Dẹ̀lílà Àwọn ìjòyè Fílístínì sì lọ bá obìnrin náà, wọ́n sọ fún un wí pé, Bí ìwọ bá le tàn án kí òun sì fi àsírí agbára rẹ̀ hàn ọ́, àti bí àwa ó ti lè borí rẹ̀, kí àwa sì dè é kí àwa sì ṣẹ́gun rẹ̀ Ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wa yóò sì fún ọ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà fàdákà Torí náà Dẹ̀lílà sọ fún Sámúsónì pé, Sọ àsírí agbára ńlá rẹ fún mi àti bí wọ́n ti le dè ọ́, àti bí wọ́n ṣe lè borí rẹ Sámúsónì dá a lóhùn wí pé, Bí ẹnikẹ́ni bá fi okùn tútù méje tí ẹnìkan kò sá gbẹ dè mí, èmi yóò di aláìlágbára bí i gbogbo àwọn ọkùnrin yóòkù Àwọn olóyè Fílístínì sì mú okùn tútù méje tí ẹnikẹ́ni kò sá gbẹ wá fún Dẹ̀lílà òun sì fi wọ́n dè é Nígbà tí àwọn ènìyàn tí sá pamọ́ sínú yàrá, òun pè pé, Sámúsónì àwọn Fílístínì ti dé láti mú ọ Ṣùgbọ́n òun já àwọn okùn náà bí òwú ti í já nígbà tí ó bá wà lẹ́bàá iná Torí náà wọn kò mọ àsírí agbára rẹ̀ Dẹ̀lílà sì sọ fún Sámúsónì pé, ìwọ ti tàn mí o sì purọ́ fún mi Wá báyìí kí o sì sọ bí a ti ṣe le dè ọ́ Òun dáhùn pé, Bí wọ́n bá lè fi okùn túntún tí ẹnikẹ́ni kò tíì lò rí dì mí dáadáa, èmi yóò di aláìlágbára, èmì yóò sì dàbí àwọn ọkùnrin yóòkù Dẹ̀lílà sì mú àwọn okùn túntún, ó fi wọ́n dì í Nígbà tí àwọn ọkùnrin Fílístínì ti fi ara pamọ́ sínú yàrá, òun kígbe sí i pé, Sámúsónì àwọn Fílístínì dé láti mú ọ, òun sì já okùn náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ bí òwú Dẹ̀lílà sì tún sọ fún Sámúsónì pé, títí di ìsinsìn yìí ìwọ sì ń tún tàn mí, o sì tún purọ́ fún mi Sọ fún mi ọ̀nà tí wọ́n fi le dè ọ́, Sámúsónì dá a lóhùn pé, Bí ìwọ bá hun ìdí irun méjèèje tí ó wà ní orí mi pẹ̀lú okùn, tí ó sì le dáadáa kí o sì fi ẹ̀mú mú un mọ́lẹ̀, èmi yóò di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yòkù Nígbà tí òun ti ṣùn, Dẹ̀lílà hun àwọn ìdí irun méjèèje tí ó wà ní oríi rẹ̀, ó sì fi ìhunṣọ dè wọ́n Ó sì tún pè é pé, Sámúsónì àwọn Fílístínì dé láti mú ọ Òun sì jí ní ojú oorun, ó sì fa ìdè ìhunṣọ náà tu pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n fi kàn án mọ́lẹ̀ Dẹ̀lílà sì sọ fún un pé, Èéṣe tí ìwọ fi wí pé, èmi fẹ́ràn rẹ, nígbà tí ìwọ kò fi ọkàn tán mi Èyí ni ìgbà kẹta tí ìwọ ti tàn mí jẹ, tí ìwọ kò sì sọ àsírí ibi tí agbára ńlá rẹ gbé wà fún mi Ó sì ṣe nígbà tí ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ ọ́ ní ojoojúmọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí dé bi pé ó ṣú u dé òpin ẹ̀mí rẹ̀ Òun sì sọ ohun gbogbo tí ó wà ní ọkàn rẹ̀ fún un Ó ní, Abẹ kò tí ì kan orí mi rí, nítorí pé Násírì, ẹni ìyàṣọ́tọ̀ fún Olúwa ni mo jẹ́ láti ìgbà ìbí mi wá Bí a bá fá irun orí mi, agbára mi yóò fi mí sílẹ̀, èmi yóò sì di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yóòkù Nígbà tí Dẹ̀lílà ríi pé ó ti sọ ohun gbogbo fún òun tan, Dẹ̀lílà ránṣẹ́ sí àwọn ìjòyè Fílístínì pé, Ẹ wá lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ti sọ ohun gbogbo fún mi Torí náà àwọn olóyè Fílístínì padà, wọ́n sì mú owó ìpinnu náà lọ́wọ́ Òun sì mú kí Sámúsónì sùn lórí itan rẹ̀, òun sì pe ọkùnrin kan láti fá àwọn ìdì irun orí rẹ̀ méjèèje, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun rẹ̀ Agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ Òun pè é wí pé, Sámúsónì àwọn Fílístínì dé láti mú ọ Òun jí ní ojú oorun rẹ̀, ó sì sọ pé, Èmi yóò jáde lọ bí í ti àtẹ̀yìn wá, kí èmi sì gba ara mi, kí n di òmìnira Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ pé Olúwa ti fi òun sílẹ̀ Nígbà náà ni àwọn Fílístínì mú un, wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì mú-un lọ sí Gásà Wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ dè é, wọ́n sì fi sí ibi iṣẹ́ ọlọ lílọ̀ nínú ilé túbú Ṣùgbọ́n irun orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tún hù lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a Àwọn ìjòyè, àwọn ará Fílístínì sì péjọ pọ̀ láti ṣe ìrúbọ ńlá sí Dágónì ọlọ́run wọn àti láti ṣe ayẹyẹ wọ́n wí pé, ọlọ́run wa ti fi Sámúsónì ọ̀ta wa lé wa lọ́wọ́ Nígbà tí àwọn ènìyàn rí Sámúsónì wọ́n yin ọlọ́run wọn wí pé, Ọlọ́run wa ti fi ọ̀ta wa lé wa lọ́wọ́ Àní ẹni tí ó ti run ilẹ̀ wa ẹni tí ó ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa Nígbà tí inú wọn dùn gidigidi tí wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá, wọ́n pariwo pé, ẹ mú Sámúsónì wá kí ó wá dáwa lára yá Wọ́n sì pe Sámúsónì jáde láti ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, òun sì ń ṣeré fún wọn Nígbà tí wọ́n mú un dúró láàárin àwọn òpó Sámúsónì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó di ọwọ́ rẹ̀ mú pé, Ẹ fi mí si ibi tí ọwọ́ mi yóò ti le tó àwọn òpó tí ó gbé tẹ́ḿpìlì dúró mú, kí èmi lè fẹ̀yìn tì wọ́n Ní àsìkò náà, tẹ́ḿpìlì yìí kún fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin gbogbo àwọn ìjòyè Fílístínì wà níbẹ̀, ní ókè ilé náà, níbi tí ẹgbẹ̀ẹ́dógún àwọ́n ọkùnrin àti obìnrin tí ń wòran Sámúsónì bí òun ti ń ṣeré Nígbà náà ni Sámúsónì ké pe Olúwa wí pé, Olúwa Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, rántí mi Háà Ọlọ́run jọ̀wọ́ fi agbára fún mi lẹ́ẹ̀kan yìí sí i, kí èmi lè gbẹ̀san lára àwọn Fílístínì nítorí àwọn ojú mi méjèèjì Sámúsónì sì na ọwọ́ mú àwọn òpó méjèèjì tí ó wà láàárin gbùngbùn, orí àwọn tí tẹ́ḿpìlì náà dúró lé, ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú ọ̀kan àti ọwọ́ òsì mú èkejì, ó fi ara tì wọ́n, Sámúsónì sì wí pé, Jẹ́ kí èmi kú pẹ̀lú àwọn Fílístínì! Òun sì fi agbára ńlá tì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni ilé náà wó lu àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó wà nínú rẹ̀ Báyìí ni ó pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nígbà ikú rẹ̀ ju ìgbà ayé rẹ̀ lọ Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ ní àpapọ̀ gòkè lọ wọ́n sì gbé e, wọ́n gbé e padà wá, wọ́n sì sin ín sí agbede-méjì Sórà àti Ésítaólì sínú ibojì Mánóà baba rẹ̀ Òun ti ṣe àkóso Ísírẹ́lì ní ogún ọdún Ìbọ̀rìṣà Míkà Nígbà náà ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà láti agbégbé òkè Éfúráímù sọ fún ìyá rẹ̀ pé, Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà èyí tótó kílógírámù mẹ́talá tí wọ́n jí mọ́ ọ lọ́wọ́, àti nípa èyí tí mo gbọ́ tí ìwọ ń ṣépè Kíyèsi fàdákà náà wà ní ọ̀dọ̀ mi, èmi ni mo kó o Nígbà náà ni ìyá rẹ̀ dáhùn pé, Kí Olúwa bùkún ọ ọmọ mi! Nígbà tí ó da ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ dáhùn pé, Èmi ti fi òtítọ́ inú ya sílífà náà sọ́tọ̀ sí Olúwa fún ọmọ mi láti fi dá ère dídá àti ère gbígbẹ́ Èmi yóò dá a padà fún ọ Nítorí náà òun dá sílífà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì mú igba ṣékélì fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà ẹni tí ó fi wọ́n rọ ère fínfín àti ère dídà Wọ́n sì kó wọn sí ilé Míkà Ọkùnrin náà, Míkà sì ní ojúbọ kan Òun sì ra èwù Éfódì kan, ó sì ṣe àwọn ère kan, ó sì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe àlùfáà rẹ̀ Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní ọba olúkúlùkù ṣe bí ó ti rò pé ó tọ́ ní ojú ara rẹ́ Ọ̀dọ́mọkùnrin Léfì kan wà, ẹni tí ó wá láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, ẹni tí ó ti ń gbé ní àárin ẹ̀yà Júdà, fi ìlú náà sílẹ̀ láti wá ibòmíràn láti máa gbé Ní ojú ọ̀nà àjò rẹ̀, ó dé ilẹ̀ Míkà nínú àwọn ilẹ̀ òkè Éfúráímù Míkà bi í pé, Níbo ni ó ti ń bọ̀ Ó dáhùn pé, Ọmọ Léfì ni mí láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Júdà, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé Míkà sì sọ fún un wí pé, Dúró lọ́dọ̀ mi kí ìwọ sì jẹ́ baba mi àti àlùfáà fún mi, èmi ó sì máa fún ọ ní ṣékélì mẹ́wàá fàdákà ní ọdọọdún, pẹ̀lú aṣọ àti oúnjẹ rẹ̀ Ọmọ Léfì náà sì gbà láti máa bá a gbé, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ Nígbà náà ni Míkà ya ará Léfì náà sí mímọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì di àlùfáà rẹ̀, ó sì ń gbé ilé rẹ̀ Míkà sì wí pé, Báyìí, èmi mọ̀ pé Olúwa yóò ṣe mi ní oore nítorí pé mo ní ọmọ Léfì ní àlùfáà mi Àwọn Ìran Dánì Tẹ̀dó Sí Láíṣì Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní ọba Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ẹ̀yà Dánì ń wá ilẹ̀ ti wọn, níbi tí wọn yóò máa gbé, nítorí pé títí di àkókò náà wọn kò ì tí ì pín ogún ilẹ̀ fún wọn ní ìní láàárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Nítorí náà àwọn ẹ̀yà Dánì rán àwọn jagunjagun márùn ún lọ láti Ṣórà àti Ésítaólì láti yọ́ ilẹ̀ náà wò àti láti rìn ín wò Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe ojú fún gbogbo àwọn ẹ̀yà wọn Wọ́n wí fún wọn pé, Ẹ lọ kí ẹ rin ilẹ̀ náà ká, kí ẹ sì wò ó fínnífínní Àwọn ọkùnrin náà wọ àwọn ìlú tí ó wà ní agbégbé òkè Éfúráímù, wọ́n sì dé ilé Míkà, níbi tí wọ́n sùn ní òru náà Nígbà tí wọ́n súnmọ́ tòsí ilé e Míkà, wọ́n dá ohùn ọ̀dọ́mọkùnrin Léfì náà mọ̀, torí náà wọ́n yípadà, wọ́n sì wọ inú ilé náà lọ wọ́n sì bi í pé, Tá ni ó mú ọ wa sí ibi Kí ni ìwọ ń ṣe níhìnìnyìí Èéṣe tí o fi wà ní ibí Ó sọ ohun tí Míkà ti ṣe fún un, ó fi kún un fún wọn pé, Ó gbà mí sí iṣẹ́, èmi sì ni àlùfáà rẹ̀ Wọ́n wí fún un pé, Jọ̀wọ́ béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí àwa lè mọ̀ bí ìrìnàjò wa yóò yọrí sí rere Àlùfáà náà dá wọn lóhùn pé, Ẹ máa lọ ní àlàáfíà Ìrìnàjò yín tí ẹ̀yin ń rìn bá ojú rere Ọlọ́run pàdé Àwọn ọkùnrin máràrùn náà kúrò, wọ́n sì wá sí Láìsí, níbi tí wọ́n ti rí i pé àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ ní ààbò, bí àwọn ará Ṣídónì, láì sí ìfòyà àti ní ìpamọ́ Ní ìgbà tí ilẹ̀ wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, wọ́n ní ọrọ̀ púpọ̀ Ibùgbé wọn tún jìnnà sí ti àwọn ará Ṣídónì, wọn kò fí ohunkóhun bá ẹnikẹ́ni dàpọ̀ Nígbà tí wọ́n padà sí Ṣórà àti Ésítaólì, àwọn arákùnrin wọn bi wọ́n léèrè pé, Báwo ni ibi tí ẹ lọ ti rí Kí ni ìròyìn tí ẹ mú wá Wọ́n dáhùn pé, Ẹ dìde ẹ jẹ́ kí a lọ kọlù wọ́n! A wá rí i pé ilẹ̀ náà dára gidigidi Ṣé ẹ̀yin ó sì jókòó láìsí nǹkan nípa rẹ̀ Ẹ má ṣe lọ́ra láti lọ ṣíbẹ̀ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà Nígbà tí ẹ̀yin bá dé ibẹ̀, ẹ ó ò rí àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn balẹ̀ àti ilẹ̀ tí ó tẹ́jú tí Ọlọ́run ti fi fún yín, ilẹ̀ tí kò ṣe aláìní nǹkan kan Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí ó múra ogun láti ìran Dánì, jáde lọ láti Sórà àti Ésítaólì ní mímú ra láti jagun Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá Kíríátì Jéárímì ní Júdà Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀ oòrùn Kíríátì Jéárímù ni Máhánè Dánì títí di òní yìí Láti ibẹ̀ wọ́n kọjá lọ sí àwọn ìlú agbègbè òkè Éfúráímù, wọ́n sì dé ilé Míkà Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn ún tí ó lọ yọ́ ilẹ̀ Láìsì wò sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé, Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ilé yìí ní èwù Éfódì, àwọn yóòkù ní òrìṣà, ère gbígbẹ́ àti ère dídà Ẹ mọ ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe báyìí Wọ́n sì yà sí ibẹ̀, wọ́n sì wọ ilé ọ̀dọ́mọkùnrin Léfì náà, sí ilé Míkà, wọ́n kí i Àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin ará Dánì náà tí ó hámọ́ra ogun, dúró ní àbáwọlé ẹnu odi Àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n lọ yọ́ ilẹ̀ náà wò wọlé lọ wọ́n sì kó ère gbígbẹ́ náà, éfódì náà, àwọn òrìṣà ìdílé àti ère dídà náà nígbà tí àlùfáà náà àti àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí ó hámọ́ra ogun dúró ní àbáwọ ẹnu odi náà Nígbà tí àwọn ọkùnrin yìí wọ ilé e Míkà lọ tí wọ́n sì kó ère fínfín náà, éfódì náà, àwọn òrìsà ìdílé mìíràn àti ère dídà náà, àlùfáà náà béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, Kí ni ẹ̀yin ń ṣe Wọ́n dá a lóhùn pé, Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti Ísírẹ́lì bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ Nígbà náà ni inú àlùfáà náà sì dùn, òun mú èfódì náà, àwọn òrìsà ìdílé mìíràn àti ère fínfín náà, ó sì bá àwọn ènìyàn náà lọ Wọ́n kó àwọn ọmọdé wọn, àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní wọn ṣíwájú, wọ́n yípadà wọ́n sì lọ Nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé Míkà, àwọn ọkùnrin tí ó wà ní agbégbé Míkà kó ara wọn jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dánì bá Bí wọ́n ṣe ń pariwo tẹ̀lé wọn lẹ́yìn, àwọn ará Dánì yípadà wọ́n sì bi Míkà pé, Kí ló ṣe ọ́ tí o fi pe àwọn ọkùnrin rẹ jáde láti jà Ó dáhùn pé, Ẹ̀yin kó àwọn ère tí mo ṣe, àti àlùfáà mi lọ Kí ni ó kù tí mo ní Báwo ni ẹ̀yin ò ṣe béèrè pé, Kí ló ṣe ọ́   Àwọn ọkùnrin Dánì náà dáhùn pé, Má se bá wa jiyàn, tàbí àwọn oníbínú fùfù ènìyàn lè kọlù yín, ìwọ àti àwọn ìdílé yóò sì sọ ẹ̀mí yín nù Àwọn ọkùnrin Dánì náà sì bá ọ̀nà wọn lọ Nígbà tí Míkà rí í pé wọ́n lágbára púpọ̀ fún òun, ó sì padà sí ilé rẹ̀ Wọ́n sì kó àwọn ohun tí Míkà ti ṣe àti àlùfáà rẹ̀, wọ́n sì kọjá lọ sí Láísì, ní ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà Wọ́n fi ojú idà kọlù wọ́n, wọ́n sì jó ìlú wọn run Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí pé ibi tí wọ́n ń gbé jìnà sí àwọn ará Ṣídónì, wọn kò sì ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni Ìlú náà wà ní inú àfonífojì lẹ́bá a Bẹti-Réhóbù Àwọn ará Dánì sì tún ìlú náà kọ́, wọ́n sì ń gbé inú rẹ̀ Wọ́n sọ orúkọ ìlú náà ní Dánì gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn Dánì, ẹni tí wọ́n bí fún Ísírẹ́lì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Láísì ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí Àwọn ọmọ Dánì sì gbé àwọn ère kalẹ̀ fún ara wọn níbẹ̀ Jónátanì ọmọ Gáṣómì, ọmọ Móṣè, àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni àlùfáà fún àwọn ẹ̀yà Dánì títí di àkókò tí a kó ilẹ̀ náà ní ìgbékùn Wọ́n tẹ̀ṣíwájú láti lo àwọn ère tí Míkà ṣe, ní gbogbo àkókò tí ilé Ọlọ́run wà ní Ṣílò Ọmọ Léfì Kan Àti Àlè Rẹ̀ Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì Ísírẹ́lì kò ní ọba Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Léfì tí ń gbé ibi tí ó sápamọ́ nínú àwọn agbégbé òkè Éfúráímù, mú àlè kan láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà Ṣùgbọ́n àlè rẹ̀ náà jẹ́ aláìṣòótọ́ sí i, òun fi sílẹ̀, ó sì padà lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti lo oṣù mẹ́rin ní ilé baba rẹ̀ ọkọ rẹ̀ lọ sí ibẹ̀ láti rọ̀ ọ́ pé kí ó padà sí ọ̀dọ̀ òun Nígbà tí ó ń lọ ó mú ìránṣẹ́ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì lọ́wọ́, obìnrin náà mú un wọ inú ilé baba rẹ̀ lọ, nígbà tí baba obìnrin náà rí i ó fi tayọ̀ tayọ̀ gbà á Àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà rọ̀ ọ́, ó sì borí rẹ̀ láti dá a dúró fún ìgbà díẹ̀, òun sì dúró fún ọjọ́ mẹ́ta, ó ń jẹ, ó ń mu, ó sì ń sùn níbẹ̀ Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù òun sì múra láti padà lọ, ṣùgbọ́n baba ọmọbìnrin náà wí fún àna rẹ̀ pé, Fi ohun jíjẹ díẹ̀ gbé inú ró nígbà náà kí ìwọ máa lọ Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jókòó wọn láti jọ jẹun àti láti jọ mu Lẹ́yìn èyí ni baba ọmọbìnrin wí pé, Jọ̀wọ́ dúró ní alẹ́ yìí kí o sì gbádùn ara rẹ Nígbà tí ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, baba ìyàwó rẹ̀ rọ̀ ọ́, torí náà ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà Ní òwúrọ̀ ọjọ́ karùn ún nígbà tí ó dìde láti lọ, baba ọmọbìnrin wí pé, Fi oúnjẹ gbé ara ró Dúró de ọ̀sán! Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jọ jẹun Nígbà tí ọkùnrin náà, pẹ̀lú àlè àti ìránṣẹ́ rẹ̀, dìde láti máa lọ, àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà ní, Wò ó ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, dúró níbí, ọjọ́ ti lọ Dúró kí o sì gbádùn ara rẹ Ìwọ lè jí ní àárọ̀ kùtùkùtù ọ̀la kí ìwọ sì máa lọlé Ṣùgbọ́n nítorí pé òun kò fẹ́ dúró mọ́ níbẹ̀ ní òru náà ọkùnrin náà kúrò ó sì gba ọ̀nà Jébúsì ọ̀nà Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ méjèèjì tí ó fi dì í ní gàárì àti àlè rẹ̀ Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jébúsì tí ilẹ̀ ti fẹ́ ṣú tan, ìránṣẹ́ náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a dúró ní ìlú yìí tí í ṣe ti àwọn ará Jébúsì kí a sì sùn níbẹ̀ Ọ̀gá rẹ̀ dá a lóhùn pé, Rárá o, àwa kì yóò wọ ìlú àwọn àjèjì, àwọn tí olùgbé ibẹ̀ kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, a ó ò dé Gíbíà Ó fi kún un pé, ẹ wá ẹ jẹ́ kí a gbìyànjú kí a dé Gíbíà tàbí Rámà kí a sùn ní ọ̀kan nínú wọn Wọ́n sì tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìnàjò wọn, oòrùn wọ̀ bí wọ́n ti súnmọ́ Gíbíà tí ṣe ti àwọn Bẹ́ńjámínì Wọ́n yípadà wọ́n lọ sí inú ìlú náà láti wọ̀ ṣíbẹ̀ ní òru náà, wọ́n lọ wọ́n sì jókòó níbi gbọ̀ngàn ìlú náà, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n sínú ilé rẹ̀ láti wọ̀ sí Ní alẹ́ ọjọ́ náà ọkùnrin arúgbó kan láti àwọn òkè Éfúráímù, ṣùgbọ́n tí ń gbé ní Gíbíà ń ti ibi iṣẹ́ rẹ̀ bọ̀ láti inú oko Nígbà tí ó wòkè ó rí arìnrìnàjò náà ní gbọ̀ngàn ìlú náà, ọkùnrin arúgbó yìí bi í léèrè pé, Níbo ni ò ń lọ Níbo ni o ti ń bọ̀ Ọmọ Léfì náà dá a lóhùn pé, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà ni àwa ti ń bọ̀, àwa sì ń lọ sí agbégbé tí ó sápamọ́ ní àwọn òkè Éfúráímù níbi ti mo ń gbé Mo ti lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà, èmi sì ń lọ sí ilé Olúwa nísinsìn yìí Kò sí ẹni tí ó gbà mí sí ilé rẹ̀ Àwa ní koríko àti oúnjẹ tó tó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa àti oúnjẹ àti wáìnì fún àwa ìránṣẹ́ rẹ-èmi, ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú wa A ò ṣe aláìní ohun kankan Mo kí ọ kú ààbọ̀ sí ilé mi, ni ìdáhùn ọkùnrin arúgbó náà Èmi yóò pèṣè gbogbo ohun tí o nílò, kìkì pé kí ìwọ má ṣe sun ìta Òun sì mú wa sí ilé rẹ̀, ó ń bọ́ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wẹ ẹṣe wọn, àwọn àlejò náà jẹ, wọ́n mu Ǹjẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe àríyá, kíyèsí i, àwọn ọkùnrin ìlú náà, àwọn ọmọ Bélíálì kan, yí ilé náà ká, wọ́n sì ń lu ìlẹ̀kún wọ́n sì sọ fún baálé ilé náà ọkùnrin arúgbó náà pé, Mú ọkùnrin tí ó wọ̀ sínú ilé rẹ wá, kí àwa lè mọ̀ ọ́n Ọkùnrin, baálé ilé náà sì jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí fún un pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹyin arákùnrin mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ má ṣe hùwà búburú nítorí tí ọkùnrin yìí ti wọ ilé mi, ẹ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí Kíyèsí i, ọmọbìnrin mi ni èyí, wúndíá, àti àlè rẹ̀ àwọn ni èmi ó mú jáde wá nísinsin yìí, kí ẹ̀yin tẹ̀ wọ́n lógo, kí ẹ̀yin ṣe sí wọn bí ó ti tọ́ lójú yín ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí ni kí ẹ̀yin má ṣe hùwa òmùgọ̀ yìí sí Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà kò fetí sí tirẹ̀ Torí náà ọkùnrin náà mú àlè rẹ̀ ó sì tari rẹ̀ jáde sí wọn, wọ́n sì bá a fi ipá lòpọ̀, wọ́n sì fi gbogbo òru náà bá a lòpọ̀, nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́ Nígbà tí ojúmọ́ bẹ̀rẹ̀ sí là obìnrin náà padà lọ sí ilé tí ọ̀gá rẹ̀ wà, ó ṣubú lulẹ̀ lọ́nà, ó sì wà níbẹ̀ títí ó fi di òwúrọ̀ Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ jí tí ó sì dìde ní òwúrọ̀ tí ó sì sí ìlẹ̀kùn ilé náà, tí ó sì bọ́ sí òde láti tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, kíyèsí i àlè rẹ̀ wà ní síṣubú ní iwájú ilé, tí ọwọ́ rẹ̀ sì di òpó ẹnu ọ̀nà ibẹ̀ mú, òun sì wí fún obìnrin náà pé, Dìde jẹ́ kí a máa bá ọ̀nà wa lọ Ṣùgbọ́n òun kò dá a lóhùn Nígbà náà ni ọkùnrin náà gbé e lé orí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì kọjá lọ sí ilé e rẹ̀ Nígbà tí ó dé ilé, ó mú ọ̀bẹ ó sì gé àlè rẹ̀ ní oríkeríke sí ọ̀nà méjìlá, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì Gbogbo ẹni tí ó rí i sì wí pé, A kò ti rí i, bẹ́ẹ̀ a kò tí ì ṣe irú nǹkan yìí rí, kì í ṣe láti ọjọ́ tí Ísírẹ́lì ti jáde tí Éjíbítì wá títí di òní olónìí Ẹrò ó wò, ẹ gbìmọ̀ràn kí ẹ sọ fún wa ohun tí a ó ò ṣe! Ańgẹ́lì Ní ọjọ́ kan ańgẹ́lì Olúwa dìde kúrò láti Gígálì lọ sí Bókímù ó sì wí pé, Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, èmi sì ṣíwájú yín wá sí ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí láti fi fún àwọn baba ńlá yín Èmi sì wí pé, Èmi kì yóò yẹ májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ bá àwọn ènìyàn ilẹ̀ yí dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò wó pẹpẹ ibi ìsin òrìṣà wọn lulẹ̀ Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ṣe àìgbọ́ràn sími Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí Ní báyìí, èmi wí fún un yín pé, èmi kì yóò lé àwọn ènìyàn jáde kúrò níwájú yín ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ ẹ̀gún ní ìhà yín, àwọn òrìṣà wọn yóò sì jẹ́ ìdánwò fún un yín Bí ańgẹ́lì Olúwa sì ti sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ará Ísírẹ́lì tan, àwọn ènìyàn náà sì gbé ohùn wọn sókè wọ́n sì sunkún kíkorò, wọ́n sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Bókímù Wọ́n sì rúbọ sí Olúwa níbẹ̀ Lẹ́yìn tí Jóṣúà ti tú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ká, àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan lọ sí ilẹ̀ tí a fi fún wọn láti lọ gbà á ní ìní wọn Àwọn ènìyàn náà sin Olúwa ní gbogbo ìgbà ayé Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbààgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Ísírẹ́lì Jóṣúà ọmọ Núnì ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ẹni àádọ́fà ọdún Wọ́n sì sìnkú rẹ̀ sí ààlà ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní Tímínátì-Hérésì ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù ní àríwá òkè Gásà Ní ìgbẹ̀yìn, gbogbo ìran náà sì kú àwọn ìran tí ó tẹ̀lé wọn kò sì sin Olúwa nítorí wọn kò mọ Olúwa bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí Olúwa ṣe fún Ísírẹ́lì Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun tí ó burú níwájú Olúwa , wọ́n sì ń sin òrìṣà Bálímù Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀ ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíriṣí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú Nítorí tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Báálì àti Ásítarótù Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Olúwa fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́ Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀ta wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí Nígbà-kí-ìgbà tí àwọn Ísírẹ́lì bá jáde lọ sí ojú ogun láti jà, ọwọ́ Olúwa sì wúwo ní ara wọn, àwọn ọ̀ta a sì borí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún wọn, wọ́n sì wà nínú ìpọ́njú púpọ̀ Olúwa gbé àwọn onídájọ́ dìde sí àwọn tí ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wọn Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ wọn kò fi etí sí ti àwọn onídájọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àgbérè, wọ́n ń sin òrìṣà Wọn kò dàbí àwọn baba wọn, kíákíá ni wọ́n yípadà kúrò lọ́nà tí àwọn baba wọ́n ń tọ̀, ọ̀nà ìgbọràn sí àwọn òfin Olúwa Nígbà kí ìgbà tí Olúwa bá gbé onídàájọ́ dìde fún wọn, Olúwa máa ń wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà, a sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀ta wọn ní ìwọ̀n ìgbà tí onídàájọ́ náà bá wà láàyè nítorí àánú Olúwa wà ní ara wọn, nígbà tí wọ́n bá ké ìrora lábẹ́ àwọn tí ń tẹrí wọn ba, tí sì ń fi ìyà jẹ wọ́n Ṣùgbọ́n ní gbàrà tí onídàájọ́ bá ti kú àwọn ènìyàn náà a sì tún padà sí ọ̀nà ìbàjẹ́ àní ju ti àwọn baba wọn lọ, wọn a tẹ̀lé òrìṣà, wọ́n ń sìn wọ́n, wọn a sì forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n kọ̀ láti yàgò kúrò ní ọ̀nà ibi wọn àti agídí ọkàn wọn Ìbínú Olúwa yóò sì tún ru sí Ísírẹ́lì a sì wí pé, Nítorí tí orílẹ̀-èdè yìí ti yẹ májẹ̀mu tí mo fi lélẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò sì fetí sí mi Èmi kì yóò lé ọ̀kankan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí Jóṣúà fi sílẹ̀ nígbà tí ó kú jáde Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ èmi yóò lo àwọn orílẹ̀-èdè yìí láti fi dán Ísírẹ́lì wò, láti mọ̀ bóyá wọ́n yóò pa ọ̀nà Olúwa mọ́ àti pé bóyá wọn ó rìn nínú rẹ̀ bí àwọn baba ńlá wọn ti rìn Nítorí náà Olúwa fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kò sì lé wọn jáde, tàbí kí ó jẹ́ kí àwọn Ísírẹ́lì pa wọ́n run Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Bá Ará Bẹ́ńjámínì Jà Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti Dánì dé Bááṣébà, àti láti ilẹ̀ Gílíádì jáde bí ẹnìkan ṣoṣo wọ́n sì péjọ ṣíwájú Olúwa ni Mísípà Àwọn olórí gbogbo àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì dúró ní ipò wọn ní àpèjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ ọkùnrin ológun ti àwọn àti idà wọn Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí pé, Ẹ sọ fún wa báwo ni iṣẹ́ búburú ṣe ṣẹlẹ̀ Ará Léfì náà, ọkọ obìrin tí wọ́n pa fèsì pé, Èmi àti àlè mi wá sí Gíbíà ti àwọn ará Bẹ́ńjámínì láti sùn di ilẹ̀ mọ́ níbẹ̀ Ṣùgbọ́n ní òru àwọn ọkùnrin Gíbíà lépa mi wọ́n sì yí ilé náà po pẹ̀lú èrò láti pa mí Wọ́n fi ipá bá àlè mi lòpọ̀, òun sì kú Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí-ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbégbé ìní Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì Nísinsinyìí, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ sọ ìmọ̀ràn yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ yín Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dìde bí ẹnìkan pẹ̀lú gbólóhùn kan wí pé, Kò sí ẹnìkankan nínú wa tí yóò lọ sí àgọ́ rẹ̀ Rárá o, kò sí ẹyọ ẹnìkan tí yóò padà lọ sí ilé rẹ̀ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò se sí Gíbíà ní yìí Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa A ó ò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn ún nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì àti ọgọ́rùn ún láti inú ẹgbẹ̀rún kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún ún mẹ́wàá láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gíbíà ti àwọn ará Bẹ́ńjámínì, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì para pọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà Àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì wí pé, Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárin yín Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gíbíà yìí wá fún wa, kí àwa lé pa kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Ísírẹ́lì Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí Gíbíà láti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà Ní ẹṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ àwọn ará Bẹ́ńjámínì kó ẹgbàá mẹ́talá àwọn ọmọ ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gíbíà Ní àárin àwọn ọmọ ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára débi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàṣé Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, yàtọ̀ sí àwọn ará Bẹ́ńjámínì, ka ogún ọ̀kẹ́ àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì lọ sí Bẹ́tẹ́lì wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run Wọ́n wí pé, Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Bẹ́ńjámínì láti bá wọn jà Olúwa dáhùn pé, Júdà ni yóò kọ́ lọ Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dóti Gíbíà Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jáde lọ láti bá àwọn ará Bẹ́ńjámínì jà wọ́n sì dúró ní ipò ogun sí wọn ní Gíbíà Àwọn ọmo Bẹ́ńjámínì sì jáde láti Gíbíà wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbàá mọ́kànlá ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ojú ogun ní ọjọ́ náà Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì lọ wọ́n sunkún ní iwájú Olúwa títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa Wọ́n ni, Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa jà Olúwa dáhùn pé, Lọ bá wọn jà Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún súnmọ́ tòsí àwọn ará Bẹ́ńjámínì ní ọjọ́ kejì Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará Bẹ́ńjámínì jáde sí wọn láti Gíbíà, láti dojú kọ wọn, wọ́n pa ẹgbẹ̀sán ọkùnrin Ísírẹ́lì, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àní gbogbo àwọn ènìyàn, gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì, níbẹ̀ ni wọ́n jókòó tí wọ́n sì ń sunkún níwájú Olúwa Wọ́n gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà títí di àṣálẹ́, wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa Wọ́n béèrè pé, Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa tàbí kí a má lọ Olúwa dáhùn pé, Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì yàn àwọn ènìyàn tí ó lúgọ yí Gíbíà ká Wọ́n jáde tọ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì lọ ní ọjọ́ kẹta wọ́n sì dúró ní ipò wọn, wọ́n sì dìde ogun sí Gíbíà bí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì jáde láti pàdé wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí i ti àtijọ́ dé bi pé wọ́n pa bí ọgbọ̀n ọkùnrin ní pápá àti ní àwọn òpópó náà—àwọn ọ̀nà tí ó lọ sí Bẹ́tẹ́lì àti èkejì sí Gíbíà Nígbà tí àwọn Bẹ́ńjámínì ń wí pé, Àwa ti ń ṣẹ́gun wọn bí i ti ìṣáájú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń wí pé, Ẹ jẹ́ kí a sá kí a lè fà wọ́n kúrò ní ìlú sí ojú òpópó náà Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì dìde kúrò ní ipò wọn, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Báálì Támárì, àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tí wọ́n sápamọ́ sínú igbó jáde kúrò níbi tí wọ́n wà ní ìwọ̀ oòrùn Gíbíà Nígbà náà ni ẹgbàá márùn ún àwọn àṣàyàn ológun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbógun ti Gíbíà láti iwájú ogun náà le gidigidi dé bí i pé àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì kò funra pé ìparun wà nítòsí Olúwa ṣẹ́gun Bẹ́ńjámínì níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ẹgbàá méjìlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ọkùnrin Bẹ́ńjámínì, gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sì rí pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì fà sẹ́yìn níwájú àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì nítorí pé wọ́n fọkàn tán àwọn tí ó wà ní ibùba ní ẹ̀bá Gíbíà Àwọn ọkùnrin tí wọ́n lúgọ yára jáde wọ́n sì tètè wọ Gíbíà, wọ́n fọ́nká wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìlú náà Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti àwọn tí ó lúgọ sínú igbó ti fún ara wọn ní àmì pé, kí àwọn tí ó lúgọ fi ẹ̀ẹ́fín ṣe ìkúukùú ńlá láti inú ìlú náà, nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì yípadà, wọ́n sá gun Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun àti ní pípa àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó to ọgbọ̀n , wọ́n sì wí pé, Àwa ń ṣẹ́gun wọn bí ìgbà ìjà àkọ́kọ́ Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkúukùú ẹ̀ẹ́fín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì yípadà wọ́n sì rí ẹ̀ẹ́fín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì yípadà sí wọn, ẹ̀rù gidigidi sì ba àwọn ará Bẹ́ńjámínì nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn wà nínú ewu Wọ́n sì sá níwáju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí apá àṣálẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò le sálà kúrò lọ́wọ́ ogun náà Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó jáde láti inú àwọn ìlú wọn wá pa wọ́n run níbẹ̀ Wọ́n yí àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ká, wọ́n lépa wọn, wọ́n sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní ibi ìsinmi wọn ní agbégbé ìlà oòrùn Gíbíà Ẹgbàá mẹ́sàn án àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni jagunjagun Bí wọ́n ṣe síjú padà tí wọ́n sì ń sá lọ sí apá aṣálẹ̀ lọ sí ọ̀nà àpáta Rímónì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọkùnrin ní àwọn òpópónà Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì títí dé Gídómù wọ́n sì tún bi ẹgbàá ọkùnrin ṣubú Ní ọjọ́ náà ẹgbàá méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún jagunjagun Bẹ́ńjámínì tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta Rámónù, níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì padà sí àwọn ìlú Bẹ́ńjámínì wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀ Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun Àwọn Aya Fún Àwọn Ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti búra ní Mísípà pé Kò sí ẹnìkan nínú wa tí yóò fi ọmọ obìnrin rẹ̀ fún ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ní ìyàwó Àwọn ènìyàn náà lọ sí Bẹ́tẹ́lì ilé Ọlọ́run, níbi tí wọ́n jókòó níwájú Ọlọ́run títí di àṣálẹ́, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún kíkorò Wọ́n sunkún wí pé, Háà! Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, èéṣe tí nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì Èéṣe tí ẹ̀yà kan yóò fi run nínú Ísírẹ́lì lónìí Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì àwọn ènìyàn náà mọ pẹpẹ kan wọ́n sì rúbọ ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ìrẹ́pọ̀ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì béèrè wí pé, Èwo nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ó kọ̀ láti péjọ ṣíwájú Olúwa Torí pé wọ́n ti fi ìbúra ńlá búra pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti péjọ níwájú Olúwa ní Mísípà pípa ni àwọn yóò pa á Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì banújẹ́ fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì Wọ́n wí pé, A ti ké ẹ̀yà kan kúrò lára Ísírẹ́lì lónìí Báwo ni a ó ò ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù, nítorí àwa ti fi Olúwa búra láti má fi ọ̀kankan nínú àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya Wọ́n sì béèrè wí pé, È wo ni nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ó kọ̀ láti bá àwọn ènìyàn péjọ níwájú Olúwa ní Mísípà Wọ́n ríì pé kò sí ẹnìkankan tí ó wa láti Jabesi-Gílíádì tí ó wá sí ibùdó fún àjọ náà Nítorí pé nígbà tí wọ́n ka àwọn ènìyàn, wọ́n rí i pé kò sí ẹnìkan kan láti inú àwọn ará Jabesi-Gílíádì tí ó wà níbẹ̀ Àwọn ìjọ ènìyàn náà sì rán ẹgbàá mẹ́fà àwọn jagunjagun ọkùnrin, lọ sí Jabesi Gílíádì wọ́n fún wọn ní àṣẹ pé, ẹ lọ fi idà kọlu gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ Wọ́n ní, Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe, ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tí kì í ṣe wúndíá Wọ́n rí àwọn irinwó ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi-Gílíádì, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣílò àwọn ará Kénánì Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ránṣẹ́ àlàáfíà sí àwọn Bẹ́ńjámínì ní ihò àpáta Rímónì Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì náà sì padà ní àkókò náà, wọ́n sì fún wọn ní àwọn obìnrin Jabesi Gílíádì Ṣùgbọ́n wọn kò kárí gbogbo wọn Àwọn ènìyàn náà sì káàánú nítorí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, nítorí Olúwa fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì Àwọn olórí ìjọ àwọn ènìyàn náà wí pé, Kí ni àwa yóò ṣe láti rí aya fún àwọn ọkùnrin tí ó kù nígbà tí a ti pa gbogbo àwọn obìnrin Bẹ́ńjámínì run Wọ́n sì wí pé, Àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n là nínú àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ní láti ní ogún àti àrólé, kí ẹ̀yà kan nínú Ísírẹ́lì má ṣe di píparun kúrò ní orí ilẹ̀ Àwa kò le fi àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya, nítorí tí àwa ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣe ìbúra yìí pé Ègún ni fún ẹnikẹ́ni tí ó fi aya fún ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì   Wọ́n sì wí pé, Kíyèsí i ayẹyẹ ọlọ́dọọdún fún Olúwa wà ní Ṣílò ní ìhà àríwá Bẹ́tẹ́lì àti ìhà ìlà oòrùn òpópó náà tí ó gba Bẹ́tẹ́lì kọjá sí Ṣékémù, àti sí ìhà gúṣù Lébónà Wọ́n sì fi àṣẹ fún àwọn ará Bẹ́ńjámínì pé, Ẹ lọ kí ẹ sì fara pamọ́ nínú àwọn ọgbà àjàrà kí ẹ sì wà ní ìmúrasílẹ̀ Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin Ṣílò bá jáde láti lọ dara pọ̀ fún ijó, kí ẹ yára jáde láti inú àwọn ọgbà àjàrà wọ̀n-ọn-nì kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbé aya kan nínú àwọn ọmọbìnrin Ṣílò kí ẹ padà sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì Nígbà tí àwọn baba wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn bá fi ẹjọ́ sùn wá, àwa yóò wí fún wọn pé, Ẹ ṣe wá lóore nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́, nítorí àwa kò rí aya fún wọn ní àkókò ogun, ẹ̀yin kò sì ní jẹ̀bi, nítorí pé ẹ̀yin kọ́ ni ó fi àwọn ọmọbìnrin yín fún wọn bí aya   Èyí sì ni ohun tí àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣe Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà ń jó lọ́wọ́, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan mú ọmọbìnrin kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì gbé e lọ láti di aya rẹ̀ Wọ́n sì padà sí ilẹ̀ ìní wọn, wọ́n sì tún àwọn ìlú náà kọ́, wọ́n sì tẹ̀dó sínú wọn Ní àkókò náa, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé àti ẹ̀yà rẹ̀ olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, kò sí ọba ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì olúkúlùkù sì ń ṣe bí ó ti tọ́ ní ojú ara rẹ̀ Ótiníẹ́lì Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran túntún ní Ísírẹ́lì wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun, àwọn ará Kénánì Àwọn ìjòyè ìlú Fílístínì máràrùn, gbogbo àwọn ará Kénánì, àwọn ará Ṣídónì, àti àwọn ará Hífì tí ń gbé ní àwọn òkè Lébálónì bẹ̀rẹ̀ láti òkè Báálì-Aámónì títí dé Lébò Hámátì A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Ísírẹ́lì wò bóyá wọn yóò gbọ́ran sí àwọn òfin Olúwa , èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipaṣẹ̀ Móṣè Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé láàárin àwọn ará Kénánì, àwọn ará Hítì àwọn ará Ámórì, àwọn ará Pérísì, àwọn ará Hífítì àti àwọn ará Jébúsì Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Ísírẹ́lì ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa Wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Báálímù àti Áṣérótù Ìbínú Olúwa sì ru sí Ísírẹ́lì tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kúṣánì Rísíkítaímù ọba Árámù-Náháráímù bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Ísírẹ́lì sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísírẹ́lì kígbe sí Olúwa , Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Ótíníẹ́lì ọmọ Kénánì àbúrò Kálẹ́bù tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀ Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, ó sì di onídàájọ́ Ísírẹ́lì ó sì ṣíwájú wọn lọ sí ogun Olúwa sì fi Kúṣánì-Ríṣátaímù lé Ótíníẹ́lì lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Ótíníẹ́lì fi kú Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún padà sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ṣe èyí tí ó burú ní iwájú Olúwa , fún ìdí iṣẹ́ búburú yìí Olúwa fún Égílónì, ọba àwọn Móábù ní agbára ní orí Ísírẹ́lì Pẹ̀lú ìfi ọwọ́ ṣowọ́pọ̀ ogun àwọn Ámórì àti àwọn ọmọ ogun Ámálékì ní Égílónì gbógun ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì gba ìlú Ọ̀pẹ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì sin Égílónì ọba Móábù fún ọdún méjìdínlógún Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísírẹ́lì tún ké pe Olúwa , Olúwa rán olùgbàlà sí wọn, Éhúdù ẹni tí ń lo ọwọ́ òsì, ọmọ Gérà ti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì Éhúdù ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi owó orí wọn rán sí Égílónì olú ìlú Móábù ní ọdọọdún fún ọdún mẹ́rìndínlógún Ṣùgbọ́n kí ó tó lọ ní ọdún yìí Éhúdù ti ṣe idà mímú olójú méjì kan tí gígùn rẹ̀ fẹ́ ẹ̀ tó ẹṣẹ̀ kan ààbọ̀, ó sì fi pamọ́ sínú àwọn aṣọ rẹ̀ tí ó so mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún Éhúdù gbé owó orí náà lọ bí ó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ ó sì fi fún Égílónì ẹni tí ó sanra púpọ̀ Lẹ́yìn tí ó ti fi ẹ̀bùn náà fún ọba tan, ó rán àwọn tí ó kó ẹrú náà wá lọ sí ọ̀nà wọn Ṣùgbọ́n ní ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí wọ́n ti gbẹ́ òkúta, òun padà ṣẹ́yìn, ó sì wí fún ọba pé, Mo ní ọ̀rọ̀ àsírí láti bá ọ sọ Ọba sì wí pé Ẹ dákẹ́! Gbogbo àwọn tí ń sọ sì jáde síta kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ Éhúdù lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti jókòó ní iyàrá ìtura rẹ̀, Éhúdù sì wí fún-un pé Mo ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Bí ọba sì ti dìde ní orí ìtẹ́ rẹ̀, Éhúdù fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀ Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀ Éhúdù kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà Éhúdù ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ilẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyànu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì sí ilẹ̀kùn Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú Nígbà tí wọ́n dúró tí wọn sì ń retí, Éhúdù ti sálọ Ó ti gba ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́ òkúta lére, ó sì sálọ sí Ṣéírà Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó fọn fèrè ní orí òkè Éfúráímù, fèrè ìpè ogun, ó sì kó ogun jọ lábẹ́ ara rẹ̀ bí olórí ogun Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí Olúwa ti fi Móábù ọ̀ta yín lé yín lọ́wọ́ Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jọ́dánì tí ó lọ sí ilẹ̀ Móábù, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ará Móábù tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà Ní ọjọ́ náà ni Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ará Móábù, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún Lẹ́yìn Éhúdù, ni ṣáḿgárì ọmọ Ánátì ẹni tí ó pa ọgọ́rùn ún mẹ́fà Fílístínì pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Ísírẹ́lì kúrò nínú ìpọ́njú Dèbórà Lẹ́yìn ikú Éhúdù, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sì tún ṣẹ̀, wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa Nítorí náà Olúwa jẹ́kí Jábínì, ọba àwọn Kénánì, ẹni tí ó jọba ní Haṣórì, ṣẹ́gun wọn Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Ṣísérà ẹni tí ń gbé Hároṣeti-Hágóyímù Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Ísírẹ́lì lójú gidigidi fún ogún ọdún Ísírẹ́lì ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́ Dèbórà, wòlíì-obìnrin, aya Lápídótì ni olórí àti asíwájú àwọn ará Ísírẹ́lì ní àsìkò náà Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a ṣọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Dèbórà láàárin Rámà àti Bẹ́tẹ́lì ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù, àwọn ará Ísírẹ́lì a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn Olúwa láti ẹnu rẹ̀ Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Bárákì ọmọ Ábínóámù ẹni tí ń gbé ní Kádésì ní ilẹ̀ Náfítalì, ó sì wí fún-un pé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì pa á ní àṣẹ fún-un pé kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Náfítalì àti ẹ̀yà Ṣébúlúnì bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì ṣíwájú wọn lọ sí òkè Tábórì Èmi yóò sì fa Sísérà olórí ogun Jábínì, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kíṣónì èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀ Bárákì sì dá a lóhùn pé, Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ Dèbórà dá a lóhùn pé, ó dára, èmi yóò bá ọ lọ ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí Olúwa yóò fi Sísérà lé obìnrin lọ́wọ́ Báyìí Dèbórà bá Bárákì lọ sí Kédésì Nígbà tí Bárákì pe ẹ̀yà ṣébúlúnì àti ẹ̀yà Náfítalì sí Kédésì ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Dèbórà pẹ̀lú bá wọn lọ Ní àsìkò yìí Hébérì, ọ̀kan nínú ẹ̀yà Kẹ́nì, ti ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀yà Kénì, òun sì ń gbé ibòmíràn títí dé ibi igi óákù Ṣánanímù, tí ó wà ni agbégbé Kédésì Nígbà tí a sọ fún Ṣísérà pé Bárákì ọmọ Ábínóámù ti kó ogun jọ sí òkè Tábósì, Ṣísérà kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀run àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Háróṣétì tí àwọn orílẹ̀ èdè wá sí ọ̀dọ̀ Kíṣónì Dèbórà sì wí fún Bárákì pé, Lọ! Lónìí ni Olúwa fi Ṣísérà lé ọ lọ́wọ́, Olúwa ti lọ ṣíwájú rẹ Bárákì sì ṣíwájú, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì tẹ̀le e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tábórì Olúwa sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárin ogun Sísérà, Olúwa sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sísérà àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Bárákì Sísérà sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ó sì fi ẹṣẹ̀ sálọ Bárákì àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀ èdè, títí ó fi pa gbogbo àwọn ọmọ ogun Ṣísérà kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láàyè Ṣùgbọ́n Ṣísérà ti fi ẹṣẹ̀ sá lọ sí àgọ́ Jáélìa aya Hébérì ẹ̀yà Kénì nítorí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àlàáfíà wà láàárin Jábínì ọba Háṣórì àti ìdílé Hébérì ti ẹ̀yà Kénì Jáélì sì jáde síta láti pàdé Sísérà, ó sì wí fún-un pé, Wọlé sínú àgọ́ mi, Olúwa mi, wọlé wá má ṣe bẹ̀rù nítorí pé ààbò ń bẹ fún ọ Ó sì yà sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó Sísérà wí pé, Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu Ó sì sí awọ wàrà kan, ó sì fún-un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà Sísérà sọ fún Jáélì pé, Kí ó dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀   Ṣùgbọ́n Jáélì ìyàwó Hébérì mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó ṣùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin ó sì kú Nígbà tí Bárákì dé bí ó ti ń lépa Sísérà, Jáélì láti pàdé rẹ̀, wá, èmi yóò fi ẹni tí ìwọ ń wá hàn ọ́, báyìí ni ó tẹ̀lé e wọ inú àgọ́ lọ, kíyèsí Ṣísérà dùbúlẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú ìṣó àgọ́ ní agbárí rẹ̀ tí a ti kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin tí ó sì ti kú Ní ọjọ́ náà ni Ọlọ́run ṣẹ́gun Jábínì ọba àwọn ará Kénánì ní iwájú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì Ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì le, ó sì ń lágbára síwájú àti síwájú sí i lára Jábínì ọba Kénánì, títí wọ́n fi run òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Orin Dèbórà Nígbà náà ni Dèbórà àti Bárákì ọmọ Ábínóámù kọ orin ní ọjọ́ náà wí pé Nítorí bí àwọn olórí ti ṣíwájú ní Ísírẹ́lì, nítorí bi àwọn ènìyàn ti fi tọkàntọkàn wa, Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa ! Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ̀yin ìjòyè! Èmi yóò kọrin nípa Olúwa , èmi yóò kọrin Èmi yóò kọrin sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì Olúwa nígbà tí o jáde lọ láti Ṣéírì, nígbà tí o yan láti ilẹ̀ Édómù, ilẹ̀ mì tìtì, àwọn ọ̀run ya, ìkúùkù àwọ̀sámọ̀ da omi wọn sílẹ̀ Àwọn òkè mì tìtì ní iwájú Olúwa Ísírẹ́lì ẹni tí ó ni Ṣínáì, níwájú Olúwa ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì Ní àwọn ọjọ́ Ṣámgárì ọmọ Ánátì, Ní àwọn ọjọ́ Jáélì, a kọ àwọn ojú ọ̀nà sílẹ̀ àwọn arìnrìnàjò ń gba kọ̀rọ̀ kọ́rọ́ Àwọn akọni ìletò dínkù, wọ́n dínkù afi ìgbà tí Dèbórà dìde, ó dìde bí ìyá ní Ísírẹ́lì Nígbà tí Ísírẹ́lì bá yan Ọlọ́run àjèjì, ogun jíjà wọ ibodè ìlú a kò rí àpáta tàbí ọ̀kọ̀ láàárin àwọn ẹgbàá ní Ísírẹ́lì Inú mi yọ̀ sí àwọn aláṣẹ Ísírẹ́lì àwọn tí ó fi tínu tínu fi ara wọn rúbọ Ẹ yín Olúwa ! Ẹ kéde rẹ̀ ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun, ẹ̀yin tí ń jókòó láti se ìdájọ́, àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà, Ní ọ̀nà jìnjìn sí ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi Wọ́n ń sọ ti iṣẹ́ òdodo Olúwa níbẹ̀, àní iṣẹ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Ísírẹ́lì Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Olúwa sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ibodè Jí, jí, Dèbórà! Jí, jí, kó orin dìde! Dìde Bárákì! Kó àwọn ìgbékùn rẹ ní ìgbékùn ìwọ ọmọ Ábínóámù Nígbà náà ni ó fi àwọn tókù jọba lórí àwọn ènìyàn Olúwa fún mi ìjọba lórí àwọn alágbára Àwọn kan jáde wá láti Éfúráímù, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Ámélékì Bẹ́ńjámínì wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ Láti Mákírì ni àwọn alásẹ ti sọ̀ kalẹ̀ wá, láti Ṣébúlúnì ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́ Àwọn ọmọ aládé Ísákárì wá pẹ̀lú Dèbórà bẹ́è ni, Ísákàrì wà pẹ̀lú Bárákì, wọ́n fi ẹṣẹ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà Ní ipadò Rúbẹ́nì ni ìgbèrò púpọ̀ wà Èéṣe tí ìwọ fi jókòó láàárin agbo àgùntàn láti máa gbọ́ fèrè olùsọ́-àgùntàn Ní ipadó Rúbẹ́nì ni ìgbèrò púpọ̀ wà Gílíádì jókòó ní òkè odò Jọ́dánì Èéṣe tí Dánì fi jókòó nínú ọkọ̀ ojú omi Ásérì jòkòó ní etí bèbè òkun, ó sì n gbé èbúté rẹ̀ Àwọn ènìyàn Ṣébúlúnì fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Náfítalì ní ibi gíga pápá Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà àwọn ọba Kénánì jà ní Tánákì ní etí odo Mégídò, ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wá láti ibùjókòó wọn ni wọ́n ti bá Ṣísérà jà Odò Kísónì agbá wọn lọ, odò àtijọ́ náà, odò Kíṣónì Má a yan lọ ìwọ ọkàn mi, jẹ́ alágbára pẹ̀lú! Nígbà náà ni pátakò ẹṣẹ̀ ẹsin ki ilẹ̀, nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn Ẹ fi Mérósì, bú ni ańgẹ́lì Olúwa wí Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ gégùn ún kíkorò, nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ OLÚWÁ, láti dojúkọ àwọn alágbára Alábùkún jùlọ nínú àwọn ọmọ obìnrin ni Jáélì, aya Hébérì ará Kénì, alábùkún jùlọ nínú àwọn obìnrin tí ń gbé inú àgọ́ Ó bèèrè omi, ó fún un ní wàrà ó fi àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́la fún un ni wàrà dídì Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́, ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà Ó kan Ṣísérà mọ́lẹ̀ pẹ̀lú òòlù ọwọ́ rẹ̀, ó fọ́ ọ ní orí, Ó kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ sinsiǹ Ní ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ ó ṣubú ó dúbúlẹ̀ Ní ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wó lulẹ̀ ní ibi tí ó gbé wólẹ̀ sí, níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú Ìyá Ṣísérà yọjú láti ojú fèrèsé, ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé, Èése tí kẹ̀kẹ́ ẹsin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ẹsin rẹ̀ fí dúró lẹ́yìn Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé, Wọn kò ha ti rí wọn, wọn kò ha ti pín ìkógun bọ̀ fún olúkálùkù ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan, fún Ṣísérà ìkógun aṣọ aláràbarà, ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà, àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi, gbogbo wọn tí a kó ní ogun Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ kí ó ṣègbé Olúwa ! Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀ Ilẹ̀ náà sì simi ní ogójì ọdún Gídíónì Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa , Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Mídíánì lọ́wọ́ fún ọdún méje Agbára àwọn ará Mídíánì sì pọ̀ púpọ̀ lórí àwọn Ísírẹ́lì, wọ́n sì hùwà ipá sí wọn, nítorí ìdí èyí, àwọn Ísírẹ́lì sá lọ sí àwọn orí òkè, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn nínú ihò àpáta, àti nínú ọ̀gbun àti ní ibi agbára nínú àpáta Ní ìgbàkúgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ti gbin ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Mídíánì, àwọn ará Ámélékì àti àwọn ará ìlà oòrùn mìíràn yóò wá láti bá wọn jà Wọn yóò tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà, wọn a sì bá irúgbìn wọ̀nyí jẹ́ títí dé Gásà, wọn kì í sì í fi ohun alààyè kankan ṣílẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kìbáà ṣe àgùntàn, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Wọn a máa wá pẹ̀lú ohun ọ̀sìn wọn àti àwọn àgọ́ wọn, wọn a sì dàbí eṣú nítorí i púpọ̀ wọn Ènìyàn kò sì lè ka iye àwọn ènìyàn náà bí ni àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n pọ̀ débi pé wọn kò ṣe é kà ní iye, wọn a bo ilẹ̀ náà wọn a sì jẹ ẹ́ run Àwọn ará Mídíánì sì pọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú, wọ́n sọ wọ́n di òtòsì àti aláìní, fún ìdí èyí wọ́n ké pe Olúwa nínú àdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Olúwa nítorí àwọn ará Mídíánì Olúwa fi etí sí igbe wọn, ó sì rán wòlíì kan sí wọn Ẹni tí ó wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí mo mú yín gòkè ti Éjíbítì wá, láti oko ẹrú Mo gbà yín kúrò nínú agbára Éjíbítì àti kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn aninilára yín Mo lé wọn kúrò ní iwájú yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fún yín Mo wí fún un yín pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín ẹ má ṣe sin àwọn òrìṣà àwọn ará Ámórì, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́ràn sí ohun tí mo sọ Ní ọjọ́ kan ańgẹ́lì Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù ófírà èyí ti ṣe ti Jóásìu ará Ábíésérì, níbi tí Gídíónì ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọn ọtí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Mídíánì Nígbà tí ańgẹ́lì Olúwa fara han Gídíónì, ó wí fún un pé, Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, akọni ológun Gídíónì dáhùn pé, Alàgbà, bí Olúwa bá wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo ìwọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa Níbi gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ tí àwọn baba wa ròyìn rẹ̀ fún wa nígbà tí wọ́n wí pé, Olúwa kò ha mú wa gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì wá Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Mídíánì lọ́wọ́ Olúwa sì yípadà sí i, ó sì wí fún un pé, Lọ nínú agbára tí o ní yìí, kí o sì gba àwọn ará Ísírẹ́lì sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì Èmi ni ó ń rán ọ lọ Gídíónì sì dáhùn pé, Alàgbà Báwo ni èmi ó ṣe gba Ísírẹ́lì là Ìdílé mi ni ó jẹ́ aláìlera jù ní Mànásè, àti pé èmi ni ó sì kéré jù ní ìdílé bàbá mi Olúwa sì dáhùn pé, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì pa gbogbo àwọn ará Mídíánì láì ku ẹnìkankan Gídíónì sì dáhùn pé, nísinsìn yìí tí mo bá bá ojúrere rẹ pàdé, fún mi ní àmì pé ìwọ ni ń bá mi sọ̀rọ̀ Jọ̀wọ́ má ṣe kúrò níbí títí èmi yóò fi mú ọrẹ wá fún ọ kí n sì gbé e sí iwájú rẹ Olúwa sì wí pé, Èmi yóò dúró títí ìwọ yóò fi dé Gídíónì sì yára wọ ilé lọ, ó sì pa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan, wọ́n sì ṣè é, ó sì mú ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun éfà kan ó fi ṣe àkàrà àìwú Ó gbé ẹran náà sínú agbọ̀n ṣùgbọ́n ó fi ọbẹ̀ rẹ̀ sínú ìkòkò, ó gbé wọn jáde tọ ańgẹ́lì náà wá bí ọrẹ lábẹ́ igi óákù Ańgẹ́lì Olúwa náà sì wí fún un pé, Gbé ẹran náà àti àkàrà àìwú náà, sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sí orí rẹ̀ Gídíónì sì ṣe bẹ́ẹ̀ Ańgẹ́lì Olúwa sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí ańgẹ́lì náà mọ́ Nígbà tí Gídíónì sì ti mọ̀ dájúdájú pé ańgẹ́lì Olúwa ni, ó ké wí pé, Háà! Olúwa Ọlọ́run alágbára! Mo ti rí ańgẹ́lì Olúwa ní ojú korojú! Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, Àlàáfíà! Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ kì yóò kú Báyìí ni Gídíónì mọ pẹpẹ kan fún Olúwa níbẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Àlàáfíà ni Olúwa Ó sì wà ní Ófírà ti Ábíésérì títí di òní Ní òru ọjọ́ náà Olúwa wí fún un pé, mú akọ màlúù bàbá rẹ kejì láti inú agbo, akọ màlúù ọlọ́dún méje Wó pẹpẹ Báálì baba rẹ lulẹ̀, kí o sì fọ́ ọ̀pá Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ Lẹ́yìn èyí kí o wá mọ pẹpẹ èyí tí ó yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ lórí òkè yìí Kí o lọ́ igi Áṣírà tí o ké lulẹ̀, kí o fi akọ màlúù kejì rú ẹbọ sísun sí Olúwa Gídíónì mú mẹ́wàá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún un ṣùgbọ́n, nítorí ó bẹ̀rù àwọn ará ilé bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ìlú náà kò ṣe é ní ọ̀sán, òru ni ó ṣe Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, tí àwọn ènìyàn ìlú náà jí, wọ́n rí i pé àti fọ́ pẹpẹ Báálì àti pé a ti bẹ́ igi òpó Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, a sì ti fi akọ màlúù kejì rúbọ lóríi pẹpẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ Àwọn ènìyàn ìlú náà bi ara wọn wí pé, Ta ni ó ṣe èyí Lẹ́yìn tí wọn fara balẹ̀ ṣe ìwádìí, wọ́n gbọ́ wí pé, Gídíónì ọmọ Jóásì ni ó ṣe é Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Jóásì wí pé, Mú ọmọ rẹ jáde wá Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Báálì lulẹ̀ ó sì ti ké òpó Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n Jóásì bi àwọn èrò tí wọ́n fi ìbínú dúró tì í wí pé, Ẹ̀yin yóò ha gbìjà Báálì bí Ẹ̀yin yóò ha gbà á sílẹ̀ bí Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìjà rẹ̀ kíkú ni yóò kú ní òwúrọ̀ Bí Báálì bá ṣe Ọlọ́run ní tòótọ́ yóò jà fún ara rẹ̀ bí ẹnikẹ́ni bá wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀ Fún ìdí èyí ní ọjọ́ náà wọ́n pe Gídíónì ní Jérúbáálì wí pé, Jẹ́kí Báálì bá a jà, nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Báálì Láìpẹ́ jọjọ àwọn ogun àwọn Mídíánì, ti àwọn Ámálékì àti ti àwọn ènìyàn ìhà ìlà oòrùn yóòkù kó ara wọn jọ pọ̀ ní ìṣọ̀kan, wọ́n sì kọjá Jọ́dánì wọ́n sì tẹ̀dó sí àfonífojì Jésírẹ́lì Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Gídíónì, ó sì fun fèrè ìpè, láti pe àwọn ará Ábíésérì láti tẹ̀lé òun Ó rán àwọn oníṣẹ́ la ilẹ̀ Mánásè já pé kí wọ́n dira ogun, àti sí Ásérì, Ṣébúlúnì àti Náfítalì gbogbo pẹ̀lú sì lọ láti pàdé wọn Gídíónì wí fún Ọlọ́run pé, Bí ìwọ yóò bá gba Ísírẹ́lì là nípaṣẹ̀ mi bí ìwọ ti ṣe ìlérí— kíyèsí, èmi yóò fi awọ irun àgùntàn lé ilẹ̀ ìpakà ní alẹ́ òní Bí ìrì bá ṣẹ̀ sí orí awọ yìí nìkan tí gbogbo ilẹ̀ yóòkù sì gbẹ, nígbà náà ni èmi yóò mọ̀ lóòótọ́ pé ìwọ yóò gba Ísírẹ́lì là nípaṣẹ̀ mi bí ìwọ ti sọ Èyí ni ó sì ṣẹlẹ̀ Nígbà tí Gídíónì jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ó sì fún irun àgùntàn náà, páànù omi kan sì kún Gídíónì sì tún wí fún Olúwa pé, Jọ̀wọ́ má ṣe bínú sí mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí n tún wá ìdánilójú kan sí i, èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí n fi awọ irun yìí ṣe ìdánwò kan síi Ní àsìkò yìí, jẹ́ kí awọ irun yìí gbẹ kí gbogbo ilẹ̀ sì tutù pẹ̀lú ìrì Ní òru náà Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀, awọ irun àgùntàn nìkan ni ó gbẹ gbogbo ilẹ̀ yóòkù sì tutù nítorí ìrì Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Jérúb-báálì pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó ogun jọ lẹ́bá a oríṣun Háṣódì Àwọn ogun Mídíánì sì wà ní apá àríwá tí wọ́n ní àfonífojì tí ó wà ní ẹ̀bá òkè Mórè Olúwa wí fún Gídíónì pé, Àwọn ọmọ ogun tí o kó jọ sọ́dọ̀ ti pọ̀ jù fún mi láti fi àwọn ogun Mídíánì lé wọn lọ́wọ́, kí Ísírẹ́lì má ba à gbé ara rẹ̀ ga sí mi wí pé agbára òun ni ó gbà á là, sì kéde sí àwọn ènìyàn nísinsìn yìí pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbọ̀n, tí ó sì ń bẹ̀rù lè padà sẹ́yìn, kí ó sì kúrò lórí òkè Gílíádì   Báyìí ni Gídíónì ṣe ya àwọn ènìyàn náà Ẹgbẹ̀rúnméjìlélógún ọkùnrin sì padà sẹ́yìn àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì dúró Olúwa sì tún sọ fún Gídíónì pé, Àwọn ènìyàn yìí sì tún pọ̀ jù Kó wọn lọ sí ibi tí omi wà, èmi yóò sì yọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọ Bí mo bá wí pé eléyìí yóò bá ọ lọ yóò lọ, ṣùgbọ́n tí mo bá sọ pé, Eléyìí kò ní bá ọ lọ, òun kò gbọdọ̀ lọ Gídíónì sì kó àwọn ọkùnrin náà lọ sí ibi ìṣun omi Níbẹ̀ ni Olúwa ti wí fún un pé, Kí ó pín àwọn ènìyàn náà sí ọ̀nà méjì Ya àwọn tí ó fi ahọ́n wọn lá omi bí ajá kúrò lára àwọn tí ó kúnlẹ̀ láti mu omi pẹ̀lú ọwọ́ wọn Ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin ni ó lá omi pẹ̀lú ahọn wọn Gbogbo àwọn ìyókù ni ó kúnlẹ̀ láti mu mi Olúwa wí fún Gídíónì pé, Àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin tí ó lá omi ni èmi yóò lò láti gbà yín là àti láti fi ogun Mídíánì lé yín lọ́wọ́ Jẹ́ kí àwọn tókù padà sí ilé wọn Báyìí ni Gídíónì ṣe dá àwọn Ísírẹ́lì tí ó kù padà sí àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọ̀ọ́dúrún ọkùnrin náà dúró Àwọn wọ̀nyí sì gba gbogbo ohun èlò àti fèrè àwọn tí ó ti padà Ibùdó ogun àwọn Mídíánì wà ní àfonífojì ní ìṣàlẹ̀ Ibi tí ó wà Ní òru ọjọ́ náà Olúwa sọ fún Gídíónì pé, Dìde, dojú ogun kọ ibùdó ogun àwọn ará Mídíánì nítorí èmi yóò fi lé ọ lọ́wọ́ Ṣùgbọ́n bí ẹ̀rù àti kọlù wọ́n bá ń bà ọ́, yọ́ wọ ibùdó wọn lọ kí o mú Púrà ìránṣẹ́ rẹ lọ́wọ́ kí o sì fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú ibùdó náà Lẹ́yìn èyí ọkàn rẹ̀ yóò le láti kọlù ibùdó náà Báyìí ni òun àti Púrà ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ ẹnu ọ̀nà ibùdó yìí Àwọn ará Mídíánì, àwọn ará Ámẹ́lẹ́kì àti gbogbo ènìyàn ìlà oòrùn tó lọ ní àfonífojì bí esú ni wọ́n rí nítorí púpọ̀ wọn Àwọn ràkúnmí wọn kò sì lóǹkà, wọ́n sì pọ̀ bí yanrìn inú òkun Gídíónì dé sí àsìkò tí ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ àlá tí ó lá sí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ Ó ní, Mo lá àlá kan, nínú àlá náà mo rí àkàrà kan tó ṣe róbótó tí a fi Báálì ṣe ń yí wọ inú ibùdó àwọn ará Mídíánì, ó sì kọlu àgọ́ pẹ̀lú agbára ńlá débi wí pé àgọ́ náà dojú dé, ó sì ṣubú Ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá a lóhùn pé, Èyí kò le túmọ̀ sí ohun mìíràn ju idà Gídíónì ọmọ Jóásì ará Ísírẹ́lì lọ Ọlọ́run ti fi àwọn ará Mídíánì àti gbogbo ogun ibùdó lé e lọ́wọ́ Nígbà tí Gídíónì gbọ́ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ sin Ọlọ́run lẹ́yìn náà ni ó padà sí ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì pè wọ́n pé, Ẹ dìde! Nítorí pé Ọlọ́run yóò lò yín láti ṣẹ́gun gbogbo ogun Mídíánì Nígbà tí ó ti pín àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì sí ọ̀nà mẹ́ta, ó fi fèrè, pẹ̀lú àwọn òfìfo ìkòkò lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́, iná sì wà nínú àwọn ìkòkò náà Ó sọ fún wọn pé, Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí mo bá ṣe Nígbà tí mo bá dé igun ibùdó wọn ẹ ṣe ohun tí mo bá ṣe Nígbà tí èmi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi bá fun fèrè wa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà ni gbogbo igun ibùdó tí ẹ̀ bá wà kí ẹ fun àwọn fèrè yín kí ẹ sì hó pé, Fún Ọlọ́run àti fún Gídíónì   Gídíónì àti àwọn ọgọ́rùn-ún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé òpin ibùdó àwọn ará Mídíánì ní nǹkan bí agogo méjìlá padà Wọ́n fun fèrè wọn, wọ́n sì tún fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà ní ọwọ́ mọ́lẹ̀ Àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fun fèrè wọn, wọ́n tún fọ́ àwọn ìkòkò wọn mọ́lẹ̀ Wọ́n mú àwọn àtùpà iná wọn ní ọwọ́ òsì wọn àti fèrè tí wọ́n ń fun ní ọwọ́ ọ̀tún wọn Wọ́n pariwo hè è pé, Idà kan fún Olúwa àti fún Gídíónì! Nígbà tí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan dúró ní ipò rẹ̀ yí ibùdó àwọn Mídíánì ká, gbogbo àwọn ọmọ ogun Mídíánì ń sá káàkiri, wọ́n ń pariwo bí wọ́n ṣe ń sálọ Nígbà tí àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì fun fèrè wọn, Olúwa da ojú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan kọ ẹnìkejì rẹ̀ àti sí gbogbo ojú ọwọ́ wọn Àwọn ọmọ ogun sì sá títí dé Bẹti Sítà ní ọ̀nà Ṣérérà títí lọ dé ìpínlẹ̀ Abeli-Méhólà ní ẹ̀bá Tábátì Gbogbo àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì láti ẹ̀yà Náfítalì, Ásérì àti gbogbo Mànásè ni Gídíónì ránṣẹ́ sí, wọ́n wá wọ́n sì lé àwọn ará Mídíánì Gídíónì tún ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè Éfúráímù wí pé, Ẹ jáde wá bá àwọn ará Mídíánì jà, kí ẹ tètè gba àwọn omi Jọ́dánì títí dé Bẹti Bárà kí wọ́n tó dé bẹ̀ Báyìí ni a ṣe pe gbogbo ọkùnrin ológun Éfúráímù jáde tí wọ́n sì gba gbogbo àwọn àbáwọdò Jọ́dánì títí dé Bẹti Bárà Wọ́n mú méjì nínú àwọn olórí àwọn ará Mídíánì, àwọn náà ni Órébù àti Ṣéébù Wọ́n pa Órébù nínú àpáta Órébù, wọ́n sì pa Ṣéébù níbi tí àwọn ènìyàn ti mọ̀ fún wáìnì tí a ń pè ní ìfúntí Ṣéébù Wọ́n lé àwọn ará Mídíánì, nígbà tí wọ́n gbé orí Órébù àti Ṣéébù tọ Gídíónì wá ẹni tí ó wà ní ìhà kejì Jọ́dánì Ṣébà àti Sálímúnà Àwọn àgbààgbà ẹ̀yà Éfúráímù sì bínú gidigidi sí Gídíónì wọ́n bi í léèrè pé, kí ló dé tí o fi ṣe irú èyí sí wa Èéṣe tí ìwọ kò fi pè wá nígbà tí ìwọ kọ́kọ́ jáde lọ láti bá àwọn ará Mídíánì jagun Ohùn ìbínú ni wọ́n fi bá a sọ̀rọ̀ Ṣùgbọ́n Gídíónì dá wọn lóhùn pé, Àṣeyọrí wo ni mo ti ṣe tí ó tó fi wé tiyín Àṣàkù àjàrà Éfúráímù kò ha dára ju gbogbo ìkórè àjàrà Ábíésérì lọ bí Ọlọ́run ti fi Órébù àti Ṣéébù àwọn olórí àwọn ará Mídíánì lé yín lọ́wọ́ Kí ni ohun tí Móṣè ṣe tí ó tó fi wé e yín tàbí tí ó tó àṣeyọrí i yín Nígbà tí ó wí èyí ríru ìbínú wọn rọ lẹ̀ Gídíónì àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ̀ṣíwájú láti lépa àwọn ọ̀ta bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, wọ́n dé Jọ́dánì wọ́n sì kọjá sí òdì kejì Ó wí fún àwọn ọkùnrin Ṣúkótì pé, Ẹ fún àwọn ọmọ ogun mi ní oúnjẹ diẹ̀, nítorí ó ti rẹ̀ wọ́n, èmi sì ń lépa Ṣébà àti Ṣálímúnà àwọn ọba Mídíánì Ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Ṣúkótì fèsì pé ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Ṣébà àti Ṣálímúnà náà ni Èéṣe tí àwa yóò ṣe fún àwọn ológun rẹ ní oúnjẹ Gídíónì dá wọn lóhùn pé, Ó dára, nígbà tí Olúwa bá fi Ṣébà àti Ṣálímúnà lé mi lọ́wọ́ tán èmi yóò fi ẹ̀gún ìjù àti ẹ̀gún ọ̀gán ya ara yín Láti ibẹ̀, ó lọ sí Péníélì ó sì bẹ̀ wọ́n bẹ́ ẹ̀ gẹ́gẹ́, ṣùgbọ́n àwọn náà dá a lóhùn bí àwọn ará Súkótì ti dá a lóhùn Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ọkùnrin Péníélì pé, Nígbà tí mo bá ṣẹ́gun tí mo sì padà dé èmi yóò wọ ilé ìṣọ́ yìí Ní àsìkò náà Ṣébà àti Ṣálímúnà wà ní Kákórì pẹ̀lú ọmọogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́ kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà oòrùn, nítorí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun Gídíónì gba ọ̀nà tí àwọn dáràndáràn máa ń rìn ní apá ìhà ìlà oòrùn Nóbà àti Jógíbíà ó sì kọjú ogun sí àwọn ọmọ ogun náà nítorí wọ́n ti túra sílẹ̀ Ṣébà àti Ṣálímúnà, àwọn ọba Mídíánì méjèèjì sá, ṣùgbọ́n Gídíónì lépa wọn ó sì mú wọn, ó run gbogbo ogun wọn Gídíónì ọmọ Jóásì gba ọ̀nà ìgòkè Hérésì padà sẹ́yìn láti ojú ogun Ó mú ọ̀dọ́mọkùnrin kan ará Ṣúkótì, ó sì béèrè àwọn ìbéèrè ní ọwọ́ rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì kọ orúkọ àwọn ìjòyè Ṣúkótì mẹ́tadínlọ́gọ́rin fún un tí wọ́n jẹ́ àgbààgbà ìlú náà Nígbà náà ni Gídíónì wá ó sọ fún àwọn ọkùnrin Ṣúkótì pé, Ṣébà àti Sálímúnà nìwọ̀nyí nípa àwọn tí ẹ̀yin fi mí ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ẹ wí pé, Ṣé ó ti ṣẹ́gun Ṣébà àti Ṣálímúnà Èéṣe tí àwa ó fi fún àwọn ọmọ ogun rẹ tí ó ti rẹ̀ ní oúnjẹ   Ó mú àwọn àgbààgbà ìlú náà, ó sì fi kọ́ àwọn Ṣúkótì lọ́gbọ́n nípa jíjẹ wọ́n níyà pẹ̀lú àwọn ẹ̀gún aṣálẹ̀ àti ẹ̀gún ọ̀gàn Ó wọ ilé ìṣọ́ Péníélì, ó sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà Gídíónì bi Ṣébà àti Ṣálímúnà pé, Irú ọkùnrin tí ẹ pa ní Tábórì, bá wo ni wọ́n ṣe rí Àwọn ọkùnrin náà dàbí rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí ọmọ ọba, ní ìdáhùn wọn Gídíónì dáhùn pé, Arákùnrin mi ni wọ́n, àwọn ọmọ ìyá mi Mo fi Olúwa búra, bí ó bá ṣe pé ẹ dá ẹ̀mí wọn sí, èmi náà ò ní pa yín Ó yí padà sí Jétérì, ọmọ rẹ̀ tí ó dàgbà jùlọ, ó wí fún un pé, Pa wọ́n! Ṣùgbọ́n Jétérì kò fa idà rẹ̀ yọ láti pa wọ́n nítorí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ẹ̀rù sì bà á láti pa wọ́n Ṣébà àti Ṣálímúnà dá Gídíónì lóhùn pé, Wá pa wá fún raàrẹ, Nítorí bí ènìyàn bá ti rí bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóò rí   Gídíónì bọ́ ṣíwájú ó sì pa wọ́n, ó sì mú ohun ọ̀sọ́ tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn Àwọn ará Ísírẹ́lì wí fún Gídíónì pé, Jọba lórí wa—ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ pẹ̀lú, nítorí tí ìwọ ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì Ṣùgbọ́n Gídíónì dá wọn lóhùn pé, Èmi kì yóò jọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ mi kì yóò jọba lórí yín Olúwa ni yóò jọba lórí yín Ó sì wí pé, Mo ní ẹ̀bẹ̀ kan tí mo fẹ́ bẹ̀ yín kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín fún mi ní yẹtí kọ̀ọ̀kan láti inú ohun ti ọkàn yín láti inú ìkógun Wọ́n dáhùn pé, Tayọ̀-tayọ̀ ni àwa yóò fi wọ́n sílẹ̀ Wọ́n tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan sì ń sọ yẹtí kọ̀ọ̀kan tí ó kàn wọ́n láti ibi ìkógun ṣíbẹ̀ Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó bèèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán, ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn ún méje ìwọ̀n ṣékélì èyí tó kìlógírámù mọ́kàndínlógún ààbọ̀ , láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ eléṣé àlùkò tí àwọn ọba Mídíánì ń wọ̀ tàbí àwọn ìlẹ̀kẹ̀ tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn Gídíónì fi àwọn wúrà náà ṣe Éfódì èyí tí ó gbé kalẹ̀ ní Òfírà ìlú rẹ̀ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì sọ ara wọn di aṣẹ́wó nípa sínsìn ní ibẹ̀ Ó sì di ẹ̀ṣẹ̀ fún Gídíónì àti ìdílé rẹ̀ Báyìí ni a ṣe tẹrí àwọn ará Mídíánì ba níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tún gbérí mọ́ Ní ọjọ́ Gídíónì, Ísírẹ́lì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún Jerub-Báálì ọmọ Jóásìa padà lọ láti máa gbé ní ìlú rẹ̀ Àádọ́rin ọmọ ni ó bí, nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàwó Àlè rẹ̀, tó ń gbé ní Ṣékémù, pàápàá bí ọmọkùnrin kan fún un tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ábímélékì Gídíónì ọmọ Jóásì kú ní ògbólógbó ọjọ́ rẹ̀, ó sì pọ̀ ní ọjọ́ orí, wọ́n sì sin-ín sí ibojì baba rẹ̀ ní Ófírà ti àwọn ará Ábíésérì Láìpẹ́ jọjọ lẹ́yìn ikú Gídíónì ni àwọn ará Ísírẹ́lì ṣe àgbérè tọ Báálì lẹ́yìn, wọ́n fi Báál-Beriti ṣe òrìṣà wọn Wọn kò sì rántí Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wọn gbogbo tí ó wà ní gbogbo àyíká wọn Wọ́n kùnà láti fi inú rere hàn sí ìdílé Jérú-Báálì fún gbogbo ore tí ó ṣe fún wọn Àwọn Onídàájọ́ Ní ọjọ́ kan Ábímélékì ọmọ Jérúbù-Báálì lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ ní Ṣékémù ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ àti gbogbo àwọn ìbátan ìyá rẹ̀ wí pé, Ẹbi gbogbo àwọn ará Ṣékémù léèrè, Èwo ló sàn fún un yín, ṣé kí gbogbo àwọn àádọ́rin ọmọ Jérú-Báálì jọba lórí yín ni tàbí kí ẹnìkan ṣoṣo ṣe àkóso yín Ṣùgbọ́n ẹ rántí pé ẹran ara yín àti ẹ̀jẹ̀ yín ni èmi ń ṣe Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ èyí ní etí àwọn ará Ṣékémù, ọkàn wọn fà sí àti tẹ̀lé Ábímélékì torí, wọ́n sọ wí pé, Arákùnrin wa ní í ṣe Wọ́n fún un ní àádọ́rin ṣékélì fàdákà láti ilé òrìṣà Bááli-Béritì, Ábímélékì fi owó náà gba àwọn jàǹdùkú àti aláìníláárí ènìyàn tí wọ́n sì di olùtẹ̀lé rẹ̀ Ó kó wọn lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ófírà, níbẹ̀ ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ó ti pa àádọ́rin nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn Jérú-Báálì, ṣùgbọ́n Jótamù, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ Jérúb-Báálì, bọ́ yọ nítorí pé ó sá pamọ́ Gbogbo àwọn ará Ṣékémù àti àwọn ará Bẹti-Mílò pàdé pọ̀ ní ẹ̀bá igi óákù ní ibi òpó ní Ṣékémù láti fi Ábímélékì jọba Nígbà tí wọ́n sọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí fún Jótamù, ó gun orí ṣóńṣó òkè Gérísímì lọ, ó sì ké lóhùn rara pé, Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin àgbààgbà Ṣékémù, kí Olúwa le tẹ́tí sí yín Ní ọjọ́ kan àwọn igi jáde lọ láti yan ọba fún ara wọn Wọ́n pe igi Ólífì pé, Wá ṣe ọba wa   Ṣùgbọ́n igi Ólífì dá wọn lóhùn pé, Èmi yóò ha fi òróró mi sílẹ̀ èyí tí a ń lò láti fi ọ̀wọ̀ fún àwọn ọlọ́run àti ènìyàn kí èmi sì wá ṣolórí àwọn igi Àwọn igi sọ fún igi ọ̀pọ̀tọ́ pé, Wá jọba ní orí wa Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, Kí èmi fi èṣo mi tí ó dára tí ó sì dùn sílẹ̀ láti wá ṣolórí àwọn igi Àwọn igi sì tún sọ fún àjàrà pé, Wá, kí o ṣe ọba wa Ṣùgbọ́n àjàrà dáhùn pé, Ṣé kí èmi dẹ́kun àti máa so èṣo wáìnì mi èyí tí ó ń mú inú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn dùn láti máa ṣe olórí àwọn igi Ní ìparí gbogbo àwọn igi lọ bá igi ẹ̀gún wọ́n sì sọ fún un pé, Wá kí ó ṣe ọba wa Igi ẹ̀gún dá àwọn igi lóhùn pé, Bí lótítọ́ ni ẹ bá fẹ́ yàn mí ní ọba yín Ẹ sá àṣálà sí abẹ́ ìbòji mi ṣùgbọ́n tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ìná jáde láti inú igi ẹ̀gún kí ó sì jó àwọn igi Kédárì àti ti Lẹ́bánónì run! Báyìí tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yín ṣe ohun tí ó ní ọlá àti pẹ̀lú ẹ̀mí òtítọ́ ní fífi Ábímélékì jọba, tí ó bá ṣe pé ohun tí ó tọ́ ni ẹ ṣe sí Jérú-Báálì àti ìdílé rẹ̀, bí ẹ bá san ẹ̀san tó yẹ fún un Nítorí pé baba mi jà nítorí yín, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu láti gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì ṣùgbọ́n lónìí ẹ̀yin ṣọ̀tẹ̀ sí ilé baba mi, ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ẹ ti pa àwọn àádọ́rin ọmọ rẹ̀, ẹ̀yin sì ti fi Ábímélékì ọmọ ẹrú-bìnrin rẹ̀ jọba lórí àwọn ènìyàn Ṣékémù nítorí tí ó jẹ́ arákùnrin yín Bí ohun tí ẹ ṣe sí Jérú-Báálì àti ìdílé rẹ̀ bá jẹ́ ohun tí ó yẹ, tí ẹ sì ṣe òtítọ́ inú sí i, kí ẹ ní ayọ̀ nínú Ábímélékì kí òun náà sì ní ayọ̀ nínú yín Ṣùgbọ́n tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí iná jó jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ábímélékì kí ó sì jó yín run Ẹ̀yin ará Ṣékémù àti ará Bétí-Mílò, kí iná pẹ̀lú jáde láti ọ̀dọ̀ yín wá ẹ̀yin ará Ṣékémù àti ará Bétí-Mílò kí ó sì jó Ábímélékì run Lẹ́yìn tí Jótamù ti sọ èyí tan, ó sá àṣálà lọ sí Béérì, ó sì gbé níbẹ̀ nítorí ó bẹ̀rù arákùnrin rẹ̀ Ábímélékì Lẹ́yìn tí Ábímélékì ti ṣe àkóso Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́ta, Ọlọ́run rán ẹ̀mí búburú sáàárin Ábímélékì àti àwọn ará Ṣékémù, àwọn ẹni tí ó hu ìwà ọ̀tẹ̀ Ọlọ́run ṣe èyí láti gbẹ̀san àwọn ìwà búburú, àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àwọn àádọ́rin ọmọ Jérúbù-Báálì lára Ábímélékì arákùnrin wọn àti lára àwọn ènìyàn Ṣékémù, ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀ Nítorí ìkórira tí wọ́n ni sí àwọn olórí, ni Ṣékémù dẹ àwọn ènìyàn sí àwọn orí òkè láti máa dá àwọn ènìyàn tó ń kọja lọ́nà, kí wọn sì máa jà wọ́n lólè, àwọn kan ló sọ èyí fún Ábímélékì Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sí Ṣékémù, àwọn ará Ṣékémù sì gbàgbọ́ wọ́n sì fi inú tán wọn Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde lọ sí oko, wọ́n sì ṣa èṣo àjàrà wọn jọ, wọ́n fún èṣo àjàrà náà, wọ́n si ṣe àjọ̀dún nínú ilé òrìṣà wọn Nígbà tí wọ́n ń jẹ tí wọ́n ń mu wọ́n fi Ábímélékì ré Gáálì ọmọ Ébédì dáhùn pé, Ta ni Ábímélékì tàbí tani Ṣékémù tí àwa ó fi sìn ín Ọmọ Jerubu-Báálì kọ́ ní ṣe tàbí Ṣébútì kọ́ ní igbá kejì rẹ̀ Ẹ má sin àwọn ará Hámórì baba àwọn ará Ṣékémù, Èéṣe tí a ó fi sin Ábímélékì Bí àwọn ènìyàn yìí bá wà ní abẹ́ ìsàkóso mi ni! Ẹ̀yin ó bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn yín Èmi ó ò wí fún Ábímélékì pé, Kó gbogbo àwọn ogun rẹ jáde láti jà   Nígbà tí Ṣébúlù, alákoṣo ìlú náà gbọ́ ohun tí Gáálì ọmọ Ébédì sọ, inú bí i gidigidi Ó ránṣẹ́ sí Ábímélékì pé, Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá láti máa gbé ní Ṣékémù ṣùgbọ́n, wọ́n ń rú àwọn ènìyàn sókè láti sọ̀tẹ̀ sí ọ Wá ní òru kí ìwọ àti àwọn ogun rẹ sá pamọ́ dè wọ́n nínú igbó Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù bí oòrùn ti ń yọ ìwọ yóò wọ inú ìlú náà lọ láti bá a jà Yóò sì ṣe nígbà tí Gáálì àti àwọn ogun rẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá jáde sí ọ láti bá ọ jà, ìwọ yóò ṣe ohunkóhun tí o bá fẹ́ sí wọn Ábímélékì àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ sì jáde ní òru, wọ́n sì lúgọ sí ọ̀nà mẹ́rin yí Ṣékémù ká Gáálì ọmọ Ébédì jáde síta, ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ibodè ìlú náà ní àkókò tí Ábímélékì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jáde kúrò níbi tí wọn sá pamọ́ sí Nígbà tí Gáálì rí àwọn ènìyàn náà, ó sọ fún Ṣébúlù pé, Wòó, àwọn ọkùnrin kan ń bọ̀ wá, láti orí àwọn òkè! Ṣébúlù dá a lóhùn pé, àṣìṣe lò ǹ ṣe oò ríi dáadáa, òjìji òkè ni ò ń pè ní àwọn ènìyàn Gáálì ké ó ní, Wòkè, àwọn ènìyàn ń tọ̀ wá bọ̀ láti agbede-méjì ilẹ̀ wá àti ẹ̀gbẹ́ kan n sì ń bọ̀ láti ìhà igi àwọn aláfọ̀ṣẹ tí ń jẹ́ óákù-Méónénímù Nígbà náà ni Ṣébúlù dá a lóhùn pé, Níbo ni ẹnu tí ó ń ṣe ni wà báyìí Ṣe bí o wí pé, Ta ni Ábímélékì tí àwa ó fi máa sìn ín Àwọn ẹni tí ó gàn án kọ́ nìyí Jáde lọ kí o sì bá wọn jà! Gáálì sì ṣíwájú àwọn ogun ará Ṣékémù lọ kọjú Ábímélékì láti bá wọn jagun Ábímélékì sì lé e, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun ṣubú wọ́n sì gbọgbẹ́ bí wọ́n ṣe ń sáá lọ, títí dé ẹnu ọ̀nà ibùdó ìlú náà Ábímélékì dúró sí Árúmà, nígbà tí Ṣébúlù lé Gáálì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò ni Ṣékémù, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣékémù mọ́ Ní ọjọ́ kejì àwọn ará Ṣékémù sì jà lọ́ sí oko, ẹnìkan ló ṣe òfófó rẹ̀ fún Ábímélékì Ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀, ó pín wọn sí ẹgbẹ́ mẹ́ta ó sì sá pamọ́ sí inú oko Nígbà tí ó sì rí tí àwọn ènìyàn náà ń jáde kúrò nínú ìlú, ó dìde ó gbógun tì wọ́n Ábímélékì àti àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sáré síwájú, wọ́n gba ẹnu ibodè ìlú náà, wọ́n sì dúró níbẹ̀ Àwọn ẹgbẹ́ méjì tókù sì sáré sí àwọn tó wà ní oko wọ́n sì gbógun tì wọ́n Ní gbogbo ọjọ́ náà ni Ábímélékì fi bá àwọn ará ìlú náà jà, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa àwọn ènìyàn ìlú náà ó wó ìlú náà palẹ̀ pátapáta ó sì fọ́n iyọ̀ sí i Àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣékémù gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá lọ fún ààbò sí inú ilé ìsọ́ agbára Ọlọ́run Bérítì Nígbà tí wọ́n sọ fún Ábímélékì pé àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣékémù kó ara wọn jọ pọ̀ Òun àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gun òkè Sálímónì lọ Ó gé àwọn ẹ̀ka díẹ̀ pẹ̀lú àáké, ó gbé àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí sí èjìká rẹ̀ Ó sọ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé, Ẹ ṣe ohun tí ẹ rí tí mo ń ṣe yìí ní kíákíá Báyìí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gé àwọn ẹ̀ka igi wọn tẹ̀lé Ábímélékì Wọ́n kó wọn ti ilé ìṣọ́ agbára níbi tí àwọn ènìyàn sá pamọ́ sí wọ́n sì fi iná síi pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀ Gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ó tó ẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin sì kú Ábímélékì tún lọ sí Tébésì, ó yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ Ilé ìṣọ́ kan tí ó ní agbára sì wà nínú ìlú náà Gbogbo àwọn ènìyàn ìlú náà ọkùnrin àti obìnrin sá sínú ilé ìṣọ́ náà Wọ́n ti ara wọn mọ́ ibẹ̀ wọ́n sì sá lọ sí inú àjà ilé ìṣọ́ náà Ábímélékì lọ sí ìṣàlẹ̀ ilé ìṣọ́ náà, ó sì ń bá a jà Ṣùgbọ́n bí ó ti súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ìṣọ́ náà láti dáná sun ún, obìnrin kan sọ ọmọ ọlọ lé e lórí, ó sì fọ́ ọ ní agbárí Ní ojú kan náà ni ó pe ẹni tí ó ru àpáta rẹ̀ pé, Yára yọ idà rẹ kí o sì pa mí, kí wọn má ba à sọ pé, Obìnrin ni ó pa á   Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì fi ọ̀kọ̀ gún-un ó sì kú Nígbà tí àwọn ará Ísírẹ́lì rí i pé Ábímélékì kú, olúkúlùkù wọn padà sí ilé rẹ̀ Báyìí ni Ọlọ́run san ẹ̀san ìwà búburú ti Ábímélékì hù sí baba rẹ̀ ní ti pípa tí ó pa, àwọn àádọ́rin arákùnrin rẹ̀ Ọlọ́run jẹ́ kí ìwà búburú àwọn ará Ṣékémù pẹ̀lú padà sí orí wọn Ègún Jótamù ọmọ Jérú-Báálì pàápàá wá sí orí wọn Ìpè Jeremáyà Èyí ni ọ̀rọ̀ Jeremáyà ọmọ Hílíkíyà ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà ní Ánátótì ní gbígbé ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Jòṣáyà ọmọ Ámónì Ọba Júdà, Àti títí dé àsìkò Jéhóákímù ọmọ Jòṣáyà Ọba Júdà, títí dé oṣù kaàrún ọdún kọkànlá Ṣedekáyà ọmọ Jòṣáyà Ọba Júdà, nígbà tí àwọn ará Jérúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé, Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́, kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀ Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀ èdè Mo sọ pé Háà! Olúwa tí ó pọ̀ ní ipá, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀ Olúwa sọ fún mi pé, má ṣe sọ pé ọmọdé lásán ni mí O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ Olúwa sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́ Olúwa sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsìnyìí mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ Wòó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀ èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti má a kọ́, àti láti máa gbìn Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé Kí ni o rí Jeremáyà Mo sì dáhùn wí pé Mo rí ẹ̀ka igi álímọ́ńdi Olúwa sì wí fún mi pé, ó ti rí i bí ó se yẹ, torí pé mo ti ń sọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúsẹ Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ́kèjì pé, Kí ni o rí Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá Olúwa , sì wí fún mi pé, Láti apá àríwá ni a ó ti da ìdààmú sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè àríwá níjà, ni Olúwa wí Àwọn Ọba wọn yóò wá gbé ìtẹ́ wọn ró ní ojú-ọ̀nà à bá wọlé Jérúsálẹ́mù Wọn ó sì dìde sí gbogbo àyíká wọn àti sí gbogbo àwọn ìlú Júdà Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn mi nítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀, nípa rírúbọ sí Ọlọ́run mìíràn àti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pa lásẹ fún wọn Má ṣe jẹ́ kí wọn dẹ́rù bà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn Ní òní èmi ti sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè alágbára, òpó ìrin àti odi idẹ sí àwọn Ọba Júdà, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà Wọn yóò dojú ìjà kọọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́, ni Olúwa wí Ọlọ́run Àti Àwọn Òrìṣà Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ fún yín ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì Èyí ni ohun tí Olúwa wí Má se tọ ọ̀nà àwọn orílẹ̀ èdè tàbí kí ẹ jẹ́ kí àmù òfuurufú dààmú yín, nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀ èdè Nítorí pé asán ni asà àwọn ènìyàn, wọ́n gé igi láti inú igbó, oníṣẹ́-ọnà sì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀ Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe é lọ́sọ̀ọ́ Wọ́n fi òòlù kàn án àti èṣo kí ó má ba à ṣubú Wọ́n nàró bí igi ọ̀pẹ, òrìṣà wọn kò le è ṣọ̀rọ̀ Wọ́n gbọdọ̀ máa gbé wọn nítorí pé wọn kò lè rìn Má ṣe bẹ̀rù wọn wọn kò le è ṣe ibi kankan bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ Olúwa o tóbi orúkọ rẹ sì tóbi lágbára Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ Ọba àwọn orílẹ̀ èdè Nítorí tìrẹ ni, láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀ èdè àti gbogbo ìjọba wọn, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti òpè, wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò ní láárí Sílífà tí a ti kàn ni a mú wá láti Tásísì, àti wúrà láti Lépásì èyí tí àwọn onísọ́nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́n kùn ní àwọ̀ aró àti eléṣé àlùkò, èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́ Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́, òun ni Ọlọ́run alààyè, Ọba ayérayé Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì orílẹ̀ èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀ Sọ èyí fún wọn Àwọn ọlọ́run kékèèké tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run   Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀, ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ tóbi síta nípa òye rẹ̀ Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi lọ́run a sì pariwo, ó mú kí ìkuùkù ru sókè láti òpin ayé ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀ Gbogbo ènìyàn jẹ́ aláìlóye àti aláìnímọ̀, ojú sì ti gbogbo alágbára pẹ̀lú ère rẹ̀, èrú ni ère rẹ̀, kò sì sí ẹ̀mí nínú wọn Asán ni wọ́n, iṣẹ́ yẹ̀yẹ́ sì ni nígbà tí ìdájọ́ wọn bá dé, wọn yóò ṣègbé Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jákọ́bù kò sì dàbí èyí, nítorí òun ni ó ṣẹ̀dá ohun gbogbo àti Ísírẹ́lì tí ó jẹ́ ẹ̀yà ìjogún rẹ̀ Olúwa àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀ Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ìwọ tí o ń gbé ní abẹ́ ààbò Nítorí èyí ni Olúwa wí Ní àkókò yìí, èmi yóò gbọn àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ náà jáde Èmi yóò mú ìpọ́njú bá wọn, kí wọn kí ó lè rí wọn mú Ègbé ni fún mi nítorí ìpalára mi! Ọgbẹ́ mi jẹ́ èyí tí kò lè sàn, bẹ́ẹ̀ ni mọ sọ fún ara mi, Èyí ni àìsàn mi, mo sì gbọdọ̀ fi orí tì í Àgọ́ mi bàjẹ́, gbogbo okùn rẹ̀ sì já Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́ Kò sí ẹnìkankan pẹ̀lú mi mọ́, báyìí kò sí ẹni tí yóò ná àgọ́ mi tàbí ṣe ibùgbé fún mi Àwọn olùsọ́ àgùntàn jẹ́ aláìlóye, wọn kò sì wá Olúwa nítorí náà wọn kì yóò ṣe rere àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká Fetísílẹ̀ ariwo ìdàrúdàpọ̀ ńlá náà ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá, yóò sì sọ ìlú Júdà di ahoro àti ihò jàkùmọ̀ Èmi mọ̀ Olúwa wí pé ayé ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀, kì í ṣe fún ènìyàn láti gbe igbésẹ ara rẹ̀ Tún mi ṣe Olúwa , pẹ̀lú ìdájọ́ nìkan kí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ Kí ìwọ má ṣe sọ mí di òfo Tú ìbínú rẹ síta sórí àwọn orílẹ̀ èdè tí kò mọ̀ ọ́, sórí àwọn ènìyàn tí wọn kò pe orúkọ rẹ Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jákọ́bù run, wọ́n ti jẹ ẹ́ run pátapáta, wọ́n sì ti ba ilẹ̀ ibùgbé rẹ̀ jẹ́ Ọ̀tẹ̀ Sí Jérúsálẹ́mù Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí o sì sọ wọ́n fún àwọn ènìyàn Júdà, àti gbogbo àwọn tó ń gbé ni Jérúsálẹ́mù Sọ fún wọn wí pé èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Ègbé ni fún ẹni náà tí kò pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́ Àwọn májẹ̀mú tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, nígbà tí mo mú wọn jáde láti Éjíbítì, láti ìléru ìyọ́rin wá Mo wí pé, Ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo pa láṣẹ fún un yín Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ènìyàn mi Èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run yín Nígbà náà ni Èmi ó sì mú ìlérí tí mo búra fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ láti fún wọn ní ilẹ̀ tí ó ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, ilẹ̀ tí ẹ ní lónìí Mo sì dáhùn wí pé, Àmí, Olúwa Olúwa wí fún mi pé, Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Júdà àti ní ìgboro Jérúsálẹ́mù pé, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ìlérí yìí, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn baba yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá títí di òní, mo kìlọ̀ fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà wí pé, Ẹ gbọ́ tèmi Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ bi ara sí i dípò èyí wọ́n tẹ̀ṣíwájú ni agídí ọkàn wọn Mo sì mú gbogbo ègún inú májẹ̀mú tí mo ti ṣèlérí, tí mo sì ti pàṣẹ fún wọn láti tẹ̀lé, tí wọn kò tẹ̀lé   Olúwa sì wí fún mi pé, Ọ̀tẹ̀ kan wà láàrin àwọn ará Júdà àti àwọn tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù Wọ́n ti padà sí ìdí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn tí ó kọ̀ láti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n ti tẹ̀lé àwọn Ọlọ́run mìíràn láti sìn wọ́n Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ti fọ́ májẹ̀mú tí mo ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí Èmi yóò mu ibi tí wọn kò ní le è yẹ̀ wá sorí wọn, bí wọ́n tilẹ̀ ké pè mí èmi kì yóò fetí sí igbe wọn Àwọn ìlú Júdà àti àwọn ará Jérúsálẹ́mù yóò lọ kégbe sí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń sun tùràrí sí àwọn òrìṣà náà kò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìgbà tí ìpọ́nju òhún bá dé Bí iye àwọn ìlú yín ṣe pọ̀ tó náà ni àwọn òrìṣà yín Ìwọ Júdà àwọn pẹpẹ tí o ti pèsè fún jíjó tùràrí sí àwọn Báálì, òrìṣà yẹ̀yẹ́ sì pọ̀ bí iye òpópó tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé Èmi kò ní dẹtí sí wọn ní ìgbà ìpọ́njú Kí ni àyànfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹ́ḿpìlì mi, bí ó ṣe ń hu oríṣiríṣi ìwà àrékérekè Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀ Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ ibi rẹ̀, inú rẹ̀ yóò máa dùn Olúwa pè ọ́ ní igi ólífì pẹ̀lú èṣo rẹ tí ó dára ní ojú Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líle ọ̀wọ́ iná ni yóò sun ún tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì dá Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Ísírẹ́lì àti Júdà ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí fún Báálì Nítorí Ọlọ́run fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí Mo ti dàbí ọ̀dọ́ àgùntàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí a mú lọ fún pípa N kò mọ̀ pé wọ́n ti gbìmọ̀ búburú sí mi wí pé Jẹ́ kí a run igi àti èso rẹ̀ jẹ́ kí a gé e kúrò ní orí ilẹ̀ alààyè, kí a mọ́ lè rántí orúkọ rẹ̀ mọ́ Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa àwọn ọmọ ogun, tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo, tí ó ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀mí àti ọkàn, jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́ Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn arákùnrin Ánátótì tí wọ́n ń lépa ẹ̀mí rẹ̀, tí wọ́n ń wí pé, Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa , bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìwọ ó kú láti ọwọ́ wa Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun sọ pé, Èmi yóò fìyà jẹ wọ́n, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn yóò tipasẹ̀ idà kú, ìyàn yóò pa àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn Kò ní ṣẹ́ku ohunkóhun sílẹ̀ fún wọn nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí àwọn ènìyàn Ánátótì ní ọdún ìjìyà wọn   Ọ̀rọ̀ Jeremáyà Olúwa , olódodo ni ọ́ nígbàkúgbà, nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédéé Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìsòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn Ó ti gbìn wọ́n, wọ́n sì ti fi egbò múlẹ̀, wọ́n dàgbà wọ́n sì so èso Gbogbo ìgbà ni ó wà ní ètè wọn, o jìnnà sí ọkàn wọn Síbẹ̀ o mọ̀ mí ní Olúwa , o ti rí mi o sì ti dán èrò mi nípa rẹ wò Wò ó, wọ́n lọ bí àgùntàn tí a fẹ́ pa Yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ pípa Yóò ti pẹ́ tó tí ọ̀gbẹlẹ̀ yóò fi wà, tí gbogbo ewéko ìgbẹ́ sì ń rọ Nítorí àwọn ènìyàn búburú ni ó ń gbé ibẹ̀ Àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ ti ṣègbé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ènìyàn ń sọ pé, Kò lè rí ohun tó ṣẹlẹ̀ síwa Bí ìwọ bá ń bá ẹlẹ́sẹ̀ díje, tí àárẹ̀ sì mú ọ, báwo ni ìwọ yóò ṣe bá ẹṣin díje Bí ìwọ bá kọsẹ̀ ní ilẹ̀ àlàáfíà, báwo ni ìwọ ó ṣe ṣe nínú ihà Jọ́dánì Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ìdílé— ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ Wọ́n ti hó lé ọ lórí Má ṣe gbà wọ́n gbọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáadáa Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀, màá fi ìní mi sílẹ̀ Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́ Ìní mi ti dàbí kìnnìún nínú igbó sí mi Ó ń bú ramúramù mọ́ mi nítorí náà mo kórìíra rẹ̀ Ìní kò ha ti dàbí ẹyẹ kanna-kánná tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì kọ tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i Lọ kí o lọ ṣe àkójọ gbogbo àwọn ẹranko búburú, kó wọn wá láti wá parun Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́ àgùntàn ni yóò sì ba oko àjàrà mi jẹ́, tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀ Wọ́n ó sọ oko dídára mi di ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀ tí kò wúlò níwájú mi, gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoro nítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀ ni àwọn apanirun ti gorí, nítorí idà Olúwa yóò pa láti ìkángun kìn-ín-ní dé ìkángun ìkejì ilẹ̀ náà kò sí ẹni tí yóò yè Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká, wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn Kí ojú kí ó tìyín nítorí èrè yín, nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa Èyí ni ohun tí Olúwa wí Ní ti gbogbo àwọn aládùúgbò mi búburú tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ogún tí mo fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì mi, Èmi yóò fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò fa ìdílé Júdà tu kúrò ní àárin wọn Ṣùgbọ́n tí mo bá fà wọ́n tu tán, Èmi yóò padà yọ́nú sí wọn Èmi yóò sì padà fún oníkálùkù ní ogún ìní rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ìní oníkálùkù Bí wọ́n bá sì kọ ìwà àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra wí pé, Olúwa ń bẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé, Olúwa wà a kọ́ ènìyàn mi láti fi Báálì búra, nígbà náà ni a ó gbé wọn ró láàrin ènìyàn mi Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀ èdè kan kò bá tẹ́tí Èmi yóò fà á tu pátapáta n ó sì run wọ́n, ni Olúwa wí Ọtí Wáìnì Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi, Lọ ra àmùrè aṣọ ọ̀gbọ́ kí o sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ kí o má sì ṣe jẹ́ kí omi kí ó kàn án Bẹ́ẹ̀ ni mo ra àmùrè gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí, mo sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ mi Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá nígbà kejì Mú àmùrè tí o rà, kí o sì fi wé ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o sì lọ sí Pérátì kí o lọ pa á mọ́ sí pàlàpálá òkúta Nígbà náà ni mo lọ pa á mọ́ ní Pérátì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí fún mi Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Olúwa sọ fún mi Lọ sí Pérátì kí o lọ mú àmùrè tí mo ní kí o pamọ́ síbẹ̀ Nígbà náà ni mo lọ sí Pérátì mo lọ wá àmùrè mi níbi tí mo pa á mọ́ sí, ṣùgbọ́n nísinsín yìí àmùrè náà ti bàjẹ́, kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́ Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé Èyí ni ohun tí Olúwa sọ Bákan náà ni èmi yóò run ìgbéraga Júdà àti ìgbéraga ńlá ti Jérúsálẹ́mù Àwọn ènìyàn búburú tí ó kùnà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí wọ́n ń lo agídí ọkàn wọn, tí ó sì ń rìn tọ àwọn òrìṣà láti sìn wọ́n, àti láti foríbalẹ̀ fún wọn, yóò sì dàbí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun Nítorí bí a ti lẹ àmùrè mọ́ ẹ̀gbẹ́ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni a lẹ agbo ilé Ísírẹ́lì àti gbogbo ilé Júdà mọ́ mi, ni Olúwa wí, kí wọn kí ó lè jẹ́ ènìyàn ògo àti ìyìn fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ gbọ́ Sọ fún wọn, Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí Gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún Nítorí náà sọ fún wọn pé, èyí ni ohun tí Olúwa wí Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú Ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni Olúwa wí Èmi kì yóò dáríjìn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti má a pa wọ́n run   Gbọ́ kí o sì fetísílẹ̀, ẹ má ṣe gbéraga, nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀ Ẹ fi ògo fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ó tó mú òkùnkùn wá, àti kí ó tó mú ẹsẹ̀ yín tàsé lórí òkè tí ó ṣókùnkùn, Nígbà tí ẹ̀yin sì ń retí ìmọ́lẹ̀, òun yóò sọ ọ́ di òjìji yóò si ṣe bi òkùnkùn biribiri Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀, Èmi yóò sunkún ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò, tí omi ẹkún, yóò sì máa ṣàn jáde, nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn Sọ fún Ọba àti ayaba pé, Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀, ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín, adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín Àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà ní Négéfì ni à ó tì pa, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti sí wọn Gbogbo Júdà ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn, gbogbo wọn ni a ó kó lọ pátapáta Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà àgùntàn tí ò ń mú yangàn Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ bí aboyún tó ń rọbí Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀ ni aṣọ rẹ fi fàya tí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe Ǹjẹ́ Ètópíà le yí àwọ̀ rẹ̀ padà Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere N ó fọ́n ọn yín ká bí i ìyàngbò tí ẹ̀fúùfù ilẹ̀ aṣálẹ̀ ń fẹ́ Èyí ni ìpín tìrẹ tí mo ti fi sílẹ̀ fún ọ, ni Olúwa wí, nítorí ìwọ ti gbàgbé mi tí o sì gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọlọ́run àjèjì N ó sí aṣọ lójú rẹ kí ẹ̀sín rẹ le hàn síta ìwà àgbèrè àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àìlójútì aṣẹ́wó rẹ! Mo ti rí ìwà ìkórìíra rẹ lórí òkè àti ní pápá Ègbé ni fún ọ ìwọ Jérúsálẹ́mù! Yóò ti pẹ́ tó tí o ó fi máa wà ní àìmọ́ Àjàkálẹ̀ Àrùn, Ìyàn àti Idà Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremáyà nípa ti àjàkálẹ̀-àrùn Júdà káàánú, àwọn ìlú rẹ̀ kérora wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn, igbe wọn sì gòkè lọ láti Jérúsálẹ́mù Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi, wọ́n lọ sí ìdí àmù ṣùgbọ́n wọn kò rí omi Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn, wọ́n sì bo orí wọn Ilẹ̀ náà sán nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo, wọ́n sì bo orí wọn Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀, torí pé kò sí koríko Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ dúró lórí òkè òfìfo wọ́n sì ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ìkokò ojú wọn kò ríran nítorí pé kò sí koríko jíjẹ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa, wá nǹkankan ṣe sí i nítorí orúkọ rẹ Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀ jù, a ti ṣẹ̀ sí ọ Ìrètí Ísírẹ́lì ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú, èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà bí arìnrìnàjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a mú lójijì pẹ̀lú ìyan, bí jagunjagun tí kò lágbára láti gba ni Ìwọ wà láàárin wa, Olúwa , orúkọ rẹ ni a sì ń jẹ́ má ṣe fi wá sílẹ̀ Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí, yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rúbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ ọkà, èmi ò ní gbà wọ́n Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyànu àti àjàkálẹ̀-àrùn pa wọ́n run Ṣùgbọ́n mo sọ pé, Áà! Olúwa tí ó pọ̀ ní ipá Wòlíì ń sọ fún wọn pé, ẹ kò rí idà tàbí ìyàn Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí   Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀ Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jérúsálẹ́mù torí idà àti ìyàn Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn Sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn báyìí pé  Jẹ́ kí omijé dà lójú mi lọ́sàn-án àti lóru láìdúró Fún wúndíá mi-àwọn ènìyàn mi tí a dá lọ́gbẹ́ àti lílù bolẹ̀ Bí mo bá lọ sí orílẹ̀ èdè náà, Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá, èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn Wòlíì àti Àlùfáà ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀   Ṣé o ti kọ Júdà sílẹ̀ pátapáta ni Ṣé o ti sá Síónì tì Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú tí a kò fi le wò wá sàn A ń retí àlàáfíà ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá, ní àsìkò ìwòsàn ìpáyà là ń rí Olúwa , a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa àti àìṣedédé àwọn baba wa lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀ Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá kí o má ṣe dà á Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀ èdè le ṣe kí òjò rọ̀ Ǹjẹ́ àwọ̀sánmọ̀ fúnra rẹ̀ rọ òjò bí Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ, nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé Kódà kí Mósè àti Sámúẹ́lì dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ! Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, Níbo ni kí a lọ Sọ fún wọn pé, Báyìí ni Olúwa wí  Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn àwọn tí a kọ ìgbékùn mọ́ sí ìgbékùn Èmi yóò rán oríṣìí ìparun mẹ́rin láti kọlù wọ́n, ni Olúwa wí, Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Mánásè ọmọ Heṣekáyà Ọba àwọn Júdà ṣe ní Jérúsálẹ́mù Ta ni yóò ṣàánú rẹ, ìwọ Jérúsálẹ́mù Ta ni yóò dárò rẹ Ta ni yóò dúró béèrè àlàáfíà rẹ O ti kọ̀ mí sílẹ̀, ni Olúwa wí Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́ lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́ Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ Èmi yóò fi atẹ fẹ́ wọn sí ẹnu ọ̀nà ìlú náà Èmi yóò mú ìsọ̀fọ̀ àti ìparun bá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọn kò tíì yí padà kúrò lọ́nà wọn Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ ju yanrìn òkun lọ Ní ọjọ́kanrí ni èmi ó mú apanirun kọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn Lójìjì ni èmi yóò mú ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóò sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn Òòrùn rẹ yóò wọ̀ lọ́sàn-án gangan, yóò di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù Èmi yóò fi àwọn tí ó bá yè wá síwájú àwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn, ni Olúwa wí Áà Ó ṣe tí ìyá mi bí mi ọkùnrin tí gbogbo ìtẹ́ tiraka tí wọ́n sì bá jà, èmi kò wín ni, bẹ́ẹ̀ ni èmi ò yá lọ́wọ́ ẹni síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré Olúwa sọ pé, Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó Dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ tẹríba níwájú rẹ nígbà ibi àti ipọ́njú Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin irin láti àríwá tàbí idẹ Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba nkànkan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jákèjádò orílẹ̀ èdè rẹ Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹ ní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínú mi yóò rán iná tí yóò jó ọ Ó yé ọ, ìwọ Olúwa rántí mi kí o sì ṣe ìtọ́jú mi gbẹ̀san mi lára àwọn tó dìtẹ̀ mi Ìwọ ti jìyà fún ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ, nínú bí mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n Àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi Nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí Ìwọ Olúwa Ọlọ́run alágbára Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrin àwọn ẹlẹ́gàn Má ṣe bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀ mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi È é ṣe tí ìrora mi kò lópin, tí ọgbẹ́ mi ń nira tí kò sì ṣe é wòsàn Ṣe ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi, gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá kí o lè máa sìn mí Tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di ọ̀gbẹnusọ mi Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí Wọn ó bá ọ jà ṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹ nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́, ni Olúwa wí Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú Ọjọ́ Àjálù Bákan náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ìyàwó, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin níbí yìí Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí wọ́n bá bí nílẹ̀ yìí, àti ìyá tí ó bí wọn àti bàbá wọn Wọn yóò kú ikú àrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí sọ̀fọ̀ fún wọn Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀ wọn ó ṣègbé pẹ̀lú ọ̀kọ̀ àti ìyàn Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀ Nítorí báyìí ni Olúwa wí Má ṣe wọ ilé tí oúnjẹ ìsìnkú wà, má se lọ ibẹ̀ láti káànú tàbí sọ̀fọ̀, nítorí mo ti mú ìbùkún, ìfẹ́ àti àánú mi kúrò lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ni Olúwa wí Àti ẹni ńlá àti kékeré ni yóò ṣègbé ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní sin wọ́n tàbí sọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóò fá irun orí wọn nítorí wọn Kò sí ẹni tí yóò fi oúnjẹ tu àwọn tí í sọ̀fọ̀ nínú, kódà kì í ṣe fún bàbá tàbí fún ìyá, kì yóò sí ẹni tí yóò fi ohun mímu tù wọ́n nínú Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí àsà wà, má ṣe jókòó jẹun tàbí mu ohun mímu Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí Ní ojú yín ní ọjọ́ yín ni òpin yóò débá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú, àti sí ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó ní ibí yìí Nígbà tí o bá sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yìí, tí wọ́n bá sì bi ọ́ wí pé, È é ṣe tí Olúwa ṣe mú búburú yìí bá wa Kí ni àṣìṣe tí àwa ṣe Kínni ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ fún wọn wí pé, Nítorí tí àwọn baba yín ti kọ̀ mí sílẹ̀, ni Olúwa wí, tí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn tí wọ́n ń bọ, tí wọ́n ń sìn, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọn kò sì tẹ̀lé òfin mi mọ́ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti ṣe búburú ju ti àwọn baba yín lọ Ní bí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ṣe ń tẹ̀lé ọkàn líle rẹ̀, dípò èyí tí ó yẹ kí ẹ fi gbọ́ tèmi Èmi yóò gbé yin kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí bàbá yín tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ rí, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti máa sìn Ọlọ́run kékèké ní ọ̀sán àti òru nítorí èmi kì yóò fi ojúrere wò yín Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá, ni Olúwa wí, tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, Dájúdájú Olúwa wà láàyè Olúwa ń bẹ Ẹni tí ó mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Éjíbítì Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, Bí Olúwa ṣe wà nítòótọ́ tí ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti ní gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó ti lé wọn Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò dá wọn padà sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn Ṣùgbọ́n báyìí, Èmi yóò ránsẹ́ sí àwọn apẹja púpọ̀, ni Olúwa wí Wọn ó sì dẹ wọ́n lẹ́yìn èyí yìí èmi yóò ránsẹ́ sí àwọn ọdẹ púpọ̀, wọn yóò dẹ wọ́n lórí gbogbo òkè ńlá àti òkè gíga, àti ní gbogbo pálapàla àpáta Ojú mi wà ní gbogbo ọ̀nà wọn, wọn kò pamọ́ fún mi bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò farasin lójú mi Èmi yóò san ẹ̀san ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn ní ìlọ́poméjì, nítorí wọ́n ti ba ilẹ̀ mi jẹ́ pẹ̀lú àwọn ère wọn aláìlẹ́mìí, wọ́n sì ti kún ohun ìní mi pẹ̀lú ẹ̀gbin òrìṣà wọn Olúwa , alágbára àti okun mi ẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú Áà! àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá láti òpin ayé wí pé, Àwọn baba ńlá wa kò ní ohunkan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìsà, ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀ Ṣé àwọn ènìyàn lè dá Ọlọ́run fún ara wọn bí Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí kì í ṣe Ọlọ́run Nítorí náà, Èmi yóò kọ́ wọn ní àkókò yìí, Èmi yóò kọ́ wọn pẹ̀lú agbára àti títóbi mi nígbà náà ni wọn ó mọ orúkọ mi ní Olúwa Pípa Ọjọ́ Ìsinmí Mọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Júdà ni a fi ṣóóṣó irin kọ sílẹ̀ èyí tí ó hàn ketekete pẹ̀lú ẹnu ṣóróṣóró sí oókan àyà wọn, àti lórí àwọn ìwo tó wà lórí pẹpẹ wọn Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ àti òpó Áṣérà lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ àti àwọn òkè gíga Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀ àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹ pẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè yín Láti ipaṣẹ̀ àìṣedéédé yín ni ẹ̀yin yóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín bí ẹrú ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀ nítorí ẹ̀yin ti mú inú bí mi, èyí tí yóò sì wà títí ayé Báyìí ni Olúwa wí Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn, tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran ara, àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá, kò ní rí ire, nígbà tí ó bá dé yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ ihà, ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa , tí ó sì fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò kò sí ìbẹ̀rù fún-un nígbà ooru, gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù kò sí ìjáyà fún-un ní ọdún ọ̀dá bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso Ọkàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, ó kọjá ohun tí a lè wòsàn, tani èyí lè yé Èmi Olúwa ń wo ọkàn àti èrò inú ọmọ ènìyàn láti ṣan èrè iṣẹ́ rẹ̀ fún-un, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé ni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìsòdodo Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀, àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè Ìtẹ́ ògo ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní ibi ilé mímọ́ wa Olúwa olùgbẹ́kẹ̀lé Ísírẹ́lì gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì gbogbo àwọn tí ó padà ṣẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ ni a ọ́ kọ orúkọ wọn sínú ekuru, nítorí wọ́n ti kọ Olúwa orísun omi ìyè wọn sílẹ̀ Wò mí sàn Olúwa , èmi yóò di ẹni ìwòsàn, gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà, nítorí ìwọ ni ìyìn mi Wọ́n sọ fún mi wí pé Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà Jẹ́ kí ó di ìmúsẹ báyìí Ni Olúwa wí Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùsọ àgùntàn rẹ, ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi, ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi, ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú, jẹ́ kí wọn ó bẹ̀rù Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn, fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi Lọ dúró ní ẹnu ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn Ọba Júdà ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu bodè Jérúsálẹ́mù Sọ fún wọ́n pé, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin Ọba Júdà àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Júdà àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù tí ń wọlé láti ẹnu-bodè yìí Báyìí ni Olúwa wí ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu-bodè Jérúsálẹ́mù Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe isẹ́kísẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín Ṣíbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ Ọlọ́rùn líle wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsí láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ti ẹnu bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kísẹ́ ní ọjọ́ náà Nígbà náà ni Ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì yóò gba ti ẹnu-bodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹsin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Júdà àti àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù yóò tẹ̀lé wọn ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Júdà àti ní agbègbè Jérúsálẹ́mù, láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì àti níbi òkè gúṣù láti orílẹ̀ èdè gíga Wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti orẹ ọkà ẹran, ọrẹ ọpẹ́ tùràrí àti ìyìn wá sí ilé Olúwa Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ti ẹnu-bodè Jérúsálẹ́mù wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu bodè Jérúsálẹ́mù tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀   Ní Ilé Amọ̀kòkò Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremáyà wá wí pe Ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀ Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́ Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀ Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé Ẹyin ilé Ísírẹ́lì, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ni Olúwa wí Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun Tí orílẹ̀ èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà níbi àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀ èdè kan tàbí ìjọba kan Tí ó sì ṣe búburú ní ojú mi, tí kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, nígbà náà ni èmi yóò tún ṣe rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún wọn Ǹjẹ́ nísìnsìnyìí, sọ fún àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn olúgbé Jérúsálẹ́mù wí pé, Báyìí ní Olúwa wí Wò ó! Èmi ń gbérò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlúkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rè ṣe Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, Kò se nǹkànkan, àwa yóò tẹ̀ṣíwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọkan wa, yóò tẹ̀lé agídí ọkàn búburú rẹ̀   Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí Ẹ bèèrè nínú orílẹ̀ èdè, ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri Ohun tí ó burú gidi ni wúndíá Ísírẹ́lì ti ṣe Ǹjẹ́ omi ojo rírí Lébánónì yóò di àwátì láti ibi àpáta Sí omi tútù tí ó jìnnà sí orísun rẹ yóò kọ̀ láti ṣàn bí Síbẹ̀ ni àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi, wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà aṣán tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn àti ọ̀nà wọn àtijọ́ Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́ àti ní ojú tí a kò kọ́ Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì di nǹkan ẹ̀gàn títí láé Gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù, wọn yóò sì mi orí wọn Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà oorùn, Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn ní ọjọ́ àjálù wọn Wọ́n sọ wí pé, Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremáyà, nítorí òfin ikọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò já sí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlùú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohun kóhun tí ó bá sọ Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa , gbọ́ ohun tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ Ṣe kí a fi rere san búburú Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi, rántí pé mo dúró níwájú rẹ, mo sì sọ̀rọ̀ ní torí wọn, láti yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọn jọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idà jẹ́ kí ìyàwó wọn aláìlọ́mọ àti opó jẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọn kí a sì fi idà pa àwọn ọdọ́mọkùnrin wọn lójú ogun Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọn nígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagun kọ lù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́ kòtò láti mú mi Wọ́n ti dẹ ìkẹkùn fún ẹṣẹ̀ mi Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa mọ gbogbo ète wọn láti pa mí, má ṣe fojú fò ibi wọn tàbí pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò lójú rẹ Jẹ́ kí a mú wọn kúrò níwájú rẹ bá wọn jà nígbà ìbínú rẹ Èyí ní ohun tí Olúwa wí Lọ ra ìkòkò lọ́dọ̀ alámọ̀, mú dání lára àwọn àgbààgbà ọkùnrin àti wòlíì Hó sí àfonífojì Bẹni Hínínónì, nítòsí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pótísẹ́dì níbẹ̀ sì ni kí o kéde ọ̀rọ̀ tí mo bá ọ sọ Kí o sì wí pé Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin Ọba àwọn Júdà àti ẹ̀yin ará Jérúsálẹ́mù Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ Dẹtí sí mi! Èmi yóò mú ìparun wá síbí, etí gbogbo wọn tó bá gbọ́ ọ yóò hó yaya Nítorí wọ́n ti gbàgbé mi, wọ́n sì ti sọ ibí di ilé fún òrìṣà àjòjì wọ́n ti sun ẹbọ nínú rẹ̀ fún òrìṣà tí àwọn baba wọn tàbí tí Ọba Júdà kò mọ̀ rí, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ aláìsẹ̀ kún ilẹ̀ yìí Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Báálì láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sí Báálì Nǹkan ni èmi kò pa láṣẹ tàbí dárúkọ tí kò sì wá láti inú ọkàn mi Nítorí náà sọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn tí a kì yóò pe ibí ní Tófẹ́tì tàbí ọmọ Hininómù, ṣùgbọ́n Àfonífojì ìpakúpa  Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Júdà àti Jérúsálẹ́mù run Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mi wọn Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀ Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀ Èmi yóò mú kí wọn jẹ ẹran ara ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin, wọn yóò sì jẹ ẹran ara wọn lásìkò ìparun wọn láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, tí ó ń wá ẹ̀mí wọn Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní oju àwọn tí ó bá ọ lọ Kí o sì sọ fún wọn pé, Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Èmi a fọ́ orílẹ̀ èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tófẹ́tì títí tí kò fi ní sí àyè mọ́ Èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí ibí yìí àti àwọn tí ń gbé ní ibí yìí ni Olúwa wí Èmi yóò mú ìlú yìí dàbí Tófẹ́tì Àwọn ilé tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù àti ti Ọba ìlú Júdà ni a ó sọ di àìmọ́ gẹ́gẹ́ bí ti ibí yìí ní Tófẹ́tì gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí àjà sí gbogbo ènìyàn tí ó sì ń da ọtí gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí Ọlọ́run mìíràn   Jeremáyà sì padà láti Tófẹ́tì níbi tí Olúwa rán an sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ó sì dúró ní gbangba Tẹ́ḿpìlì Olúwa , ó sì sọ fún gbogbo ènìyàn pé, Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísíẹ́lì wí Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò mú ìdààmú tí mo ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ bá ìlú yìí àti ìgbéríko tí ó yí i ká, nítorí ọlọ́rùn líle ni wọ́n, wọn kò si ní fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ mi   Ísírẹ́lì Kọ Ọlọ́run Sílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé Lọ kéde sí etí ìgbọ́ àwọn Jérúsálẹ́mù  Mo rántí ìfarasìn ìgbà èwe rẹ, gẹ́gẹ́ bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ mi bí i wúndíá àti bí o ṣe tẹ̀lé mi nínú aṣálẹ̀ àti nínú ìyàngbẹ ilẹ̀ Ísírẹ́lì jẹ́ mímọ́ sí Olúwa , àkọ́kọ́ èṣo ìkórè rẹ̀, gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ run ni a ó dá lẹ́bi, ìpọ́njú yóò dé bá wọn,  bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa , ẹ̀yin ìdílé Jákọ́bù àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Ísírẹ́lì Báyìí ni Olúwa wí Irú àwọn àìṣedédé wo ni baba yín rí nínú mi Tí wọ́n fi jìnnà sími Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà tí kò jámọ́ nǹkan kan àwọn fúnra wọn sì jẹ́ ènìyàn yẹpẹrẹ Wọn kò béèrè, Níbo ni Olúwa wà tí ó mú wọn, jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì, tí ó mú wa la ihà já, tí ó mu wọn la àárin àwọn aṣálẹ̀ àti òkè láàrin ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn wá ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò ti rìnrìn-àjò, tí ẹníkẹ́ni kò sì gbé Mo mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀, ẹ̀yin sì wá, ẹ sì ba ilẹ̀ náà jẹ́, ẹ sì mú àwọn ohun ogún mi di ohun ìríra Àlùfáà kò bèèrè wí pé níbo ni Olúwa wà Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọn olórí wọn sì gbógun sí mi, àwọn wòlíì sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà báálì, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà yẹpẹrẹ Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ́kan síi, ni Olúwa wí Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ Rékọjá sí ẹkùn kan kítímì, kí o sì wò ó, ránṣẹ́ sí kéda, kí o sì wò ó dáradára, wò ó kí ẹ sì wò ó bí irú nǹkan báyìí bá wà níbẹ̀ rí Orílẹ̀ èdè kan há á pa Ọlọ́run rẹ̀ dà àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀ ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́sẹ̀ méjì kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá, ni Olúwa wí Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́sẹ̀, méjì Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmi orísun omi ìyè, wọ́n sì ti wọ àmù, àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró Ísírẹ́lì há á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ẹrú nípa ìbí Kí ló há a dé tí ó fi di ìkógun Àwọn kìnnìún ké ramúramú wọ́n sì ń bú mọ́ wọn wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò Ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì ti di ìkọ̀sílẹ̀ Bákan náà, àwọn ọkùnrin Mémífísì àti Táfánésì wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ Ẹ̀yin kò há a ti fa èyí sórí ara yín nípa kíkọ Ọlọ́run sílẹ̀ nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Éjíbítì láti lọ mu omi ní Síhórì Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Àsíríà láti lọ mu omi ni odò Yúfúrátè náà Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín Ìpàdàṣẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí mọ̀ kí o sì ríi wí pé ibi àti ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ nígbà tí o ti kọ Ọlọ́run ọmọ ogun sílẹ̀, ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi, ni Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹ ìwọ wí pé, Èmi kì yóò sìn ọ́! Lóòtọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni àti lábẹ́ igi tí ó tàn kálẹ̀ ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá, Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi di àjàrà búburú àti aláìmọ́ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ àbàwọ́n àìṣedéédéé rẹ sì ń bọ̀ níwájú mi, ni Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí Báwo ni o ṣe le lọ sọ pé, Èmi kò ṣe aláìmọ́ Èmi kò ṣáà tẹ̀lé àwọn Báálì Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì wo ohun tí o ṣe Ìwọ jẹ́ abo ìbákasíẹ̀ tí ń sá sí ìhín sọ́hùn ún Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ tí ń gbé ihà tí ń fa ẹ̀fúùfù nínú ìfẹ́ inú rẹ̀ ta ni ó le è mu dúró ní àkókò rẹ̀ Kí gbogbo àwọn ọkùnrin tí í lé e má ṣe dára wọn lágara nítorí wọn ó ò rí ní àkókò oṣù rẹ̀ Má ṣe sáré títí ẹṣẹ̀ yín yóò fi wà ní ìhòòhò, tí ahọ́n yín yóò sì gbẹ Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, Kò nílò! Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì, èmi yóò sì lépa wọn lọ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójú ti olè nígbà tí a bá mú u, bẹ́ẹ̀ náà ni ilé Ísírẹ́lì yóò gba, àwọn ìjòyè wọn, àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú Wọn sọ fún igi pé, Ìwọ ni bàbá mi, àti sí òkúta wí pé, Ìwọ ni ó bí mi, wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi, wọn kò kọ ojú sí mi ṣíbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro, wọn yóò wí pé, Wá kí o sì gbà wá! Níbo wá ni àwọn Ọlọ́run tí ẹ ṣe fúnra yín há a wà Jẹ́ kí wọn wá kí wọn sì gbà yín nígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro! Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn Ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Júdà Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ni Olúwa wí Nínú aṣán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín, wọn kò sì gba ìbáwí, idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsí ọ̀rọ̀ Olúwa Àbí ilẹ̀ ńlá olókùnkùn kí ló dé tí àwọn ènìyàn mi ṣe sọ wí pé, A ní àǹfààní láti máa rìn kiri A kò sì ní wá sọ́dọ̀ rẹ mọ́ Wúndíá ha le gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ bí, tàbí ìyàwó ha le gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀ Síbẹ̀, àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi ní ọjọ́ àìníye Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́! Àwọn obìnrin tí ó tilẹ̀ burú yóò kẹ́kọ̀ọ́ láti àwọn ọ̀nà rẹ Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n bá ẹ̀jẹ̀ àwọn talákà aláìṣẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ká wọn níbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé Ṣíbẹ̀ nínú gbogbo èyí ìwọ sọ wí pé, Èmi jẹ́ aláìsẹ̀ kò sì bínú sími Èmi yóò ṣe ìdájọ́ mi lórí rẹ nítorí pé ìwọ sọ pé, Èmi kò tí ìdẹ́sẹ̀ Kí ló dé tí o fi ń lọ káàkiri láti yí ọ̀nà rẹ padà Éjíbítì yóò dójú tì ọ́ gẹ́gẹ́ bí i ti Ásíríà Ìwọ yóò sì fi ibẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ọwọ ìkáwọ́ lórí rẹ ní orí rẹ nítorí pé Olúwa ti kọ̀ àwọn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé, kì yóò sí ìrànlọ́wọ́ kankan fún ọ láti ọ̀dọ̀ wọn wá Jeremáyà Àti Pásúrì Ní ìgbà tí àlùfáà Pásúrì ọmọkùnrin Ímímérì olórí àwọn ìjòyè Tẹ́ḿpìlì Olúwa gbọ́ tí Jeremáyà ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí Ó mú kí wọ́n lù ú, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu ọ̀nà ti Bẹ́ńjámínì ní Tẹ́ḿpìlì Olúwa Ní ọjọ́ kejì tí Páṣúrì tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremáyà sì sọ fún un wí pé, orúkọ Olúwa kì í ṣe Páṣúrì fún ọ bí kò ṣe ohun ẹ̀rù Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Júdà lé Ọba Bábílónì lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Bábílónì tàbí kí ó pa wọ́n Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀ta wọn Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá Ọba Júdà Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Bábílónì Àti ìwọ Páṣúrì, gbogbo ènìyàn inú ilé rẹ yóò sì lọ ṣe àtìpó ní Bábílónì Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, tí wọn yóò sì sin ọ́ síbẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ìwọ ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún Olúwa , o tàn mí jẹ́, o sì ṣẹ́gun Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́, gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà Nígbàkúgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta èmi á sọ nípa ipá àti ìparun Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkù àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, Èmi kì yóò dárúkọ rẹ tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi tí a sé nínú egungun mi Agara dá mi ní inú mi nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn! Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé, Bóyá yóò jẹ́ di títàn, nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀, àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀ Ṣùgbọ́n Olúwa wà pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí jagunjagun alágbára Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀, wọn kì yóò sì borí Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀ Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé Olúwa alágbára, ìwọ tí ó ń dán olódodo pípé wò tí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀yà fínní-fínní, jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn, nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé Kọrin sí Olúwa ! Fi ìyìn fún Olúwa ! Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi! Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi, Tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé, A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin! Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú tí Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáànú Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀, ariwo ogun ní ọ̀sán Nítorí kò pa mí nínú, kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi, kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn, láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀ àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú Ọlọ́run Kọ Ìbéèrè Sedekáyà Sílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremáyà wá nígbà tí Ọba Sedekáyà rán Páṣúrì ọmọ Málíkíjà àti àlùfáà Sedekáyà ọmọ Mánásè síi wọ́n wí pé Wádìí lọ́wọ́ Olúwa fún wa nítorí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ń kọlù wá Bóyá Olúwa yóò ṣe ìyanu fún wa gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa Ṣùgbọ́n Jeremáyà dáhùn wí pé, Sọ fún Sedekáyà, Èyí ni Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá Ọba àti àwọn ará Bábílónì tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí Èmi gan an yóò sì bá yín jà pẹ̀lú ohun ìjà olóró nínú ìbínú àti ìrunú líle Èmi yóò sì lu gbogbo ìlú yìí, ènìyàn àti ẹranko, gbogbo wọn ni àjàkálẹ̀-àrùn yóò kọlù tí wọn yóò sì kú Olúwa sọ pé lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò fi Sedekáyà Ọba Júdà, àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó yọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ogun àti ìyàn lé Ọba Nebukadinésárì àti Bábílónì àti gbogbo ọ̀ta wọn tí ń lépa ẹ̀mí wọn lọ́wọ́ Òun yóò sì fi idà pa wọ́n, kì yóò sì ṣàánú wọn Síwájú síi, sọ fún àwọn ènìyàn, Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ Wò ó, Èmi ń fi ọ̀nà ìyè àti ikú hàn yín Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró sí ìlú yìí yóò ti ipa idà, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-àrùn kú Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jáde tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn Bábílónì tí ó ń lépa yín yóò sì yè Òun yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀ Mo ti pinnu láti jẹ ìlú yìí níyà, ni Olúwa wí A ó sì gbé e fún Ọba Bábílónì, yóò sì run ún pẹ̀lú iná Ẹ̀wẹ̀, wí fún ìdílé Ọba Júdà pé, Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ilé Dáfídì èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ  Ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ ní àràárọ̀ yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ó ń ni í lára ẹni tí a ti jà lólè bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìbínú mi yóò jáde síta, yóò sì jó bí iná Nítorí ibi tí a ti ṣe yóò sì jó láìsí ẹni tí yóò pa á Mo kẹ̀yìn sí ọ, Jérúsálẹ́mù ìwọ tí o gbé lórí àfonífojì lórí olókúta tí ó tẹ́jú, Ìwọ tí o ti wí pé, Ta ni ó le dojú kọ wá Èmi yóò jẹ ẹ́ níyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni Olúwa wí Èmi yóò mú kí iná jó ilé rẹ̀ ìyẹn yóò jó gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká rẹ   Ìdájọ́ Fún Àwọn Ọba Búburú Báyìí ni Olúwa wí, Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ààfin Ọba Júdà, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀ Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ìwọ Ọba Júdà, tí ó jókòó ní Ìtẹ́ Dáfídì, ìwọ, àwọn ènìyàn rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí ó wọlé láti ẹnu ibodè wọ̀nyí Báyìí ni Olúwa wí Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára Má ṣe hu ìwà ìpanilára, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí Nítorí bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, nígbà náà ni àwọn Ọba inú ààfin láti ẹnu ọ̀nà, wọn yóò gun kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin, àwọn àti ìránṣẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí   Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin Ọba Júdà, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gílíádì sí mi, gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lẹ́bánónì, dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn Èmi ó rán apanirun sí ọ olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀, wọn yóò sì gé àsànyàn igi kédárì rẹ lulẹ̀, wọn ó sì kó wọn jù sínú iná Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè yóò rékọjá lẹ́bàá ìlú yìí wọn yóò sì máa bi ara wọn léèrè pé, Èéṣe tí Olúwa ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí Ìdáhùn wọn yóò sì jẹ́ Nítorí tí wọ́n ti kọ májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọn ti ń fi oríbalẹ̀ fún Ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì sìn wọ́n   Nítorí náà má ṣe sunkún nítorí Ọba tí ó ti kú tàbí sọ̀fọ̀ fún àdánù rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ sunkún kíkorò fún ẹni tí a lé kúrò nílùú nítorí kì yóò padà wá mọ́ tàbí fi ojú rí ilẹ̀ tí a ti bí i Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣálúmù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà tí ó jọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn ín Òun kì yóò padà wá mọ́ Yóò kú ni ibi tí a mú u ní ìgbèkùn lọ, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́ Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìsòdodo, àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́ tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán láì san owó iṣẹ́ wọn fún wọn Ó wí pé, Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara mi àwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀, ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi A ó sì fi igi kédárì bò ó, a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́ Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kédárì, a sọ ọ́ di Ọba baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ni ó fi dára fún un Ó gbéjà òtòsì àti aláìní, ohun gbogbo sì dára fún un Ìyẹn ha kọ́ ni mímọ́ mi túmọ̀ sí ni Olúwa wí Ṣùgbọ́n ojú àti ọkàn rẹ wà lára rẹ̀ ní èrè àìsòtítọ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehóíákímù ọmọ Jòsáyà, Ọba Júdà Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un wí pé, Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi! Wọn kì yóò sọ̀fọ̀ fún un wí pé, Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe kábíyèsí! A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a wọ́ sọnù gba ti ẹnubodè Jérúsálẹ́mù Gòkè lọ sí Lẹ́bánónì, kígbe síta kí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Básánì, kí o kígbe sókè láti Ábárímù, nítorí a ti run gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ túútúú Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu, ṣùgbọ́n o sọ pé, Èmi kì yóò fetísílẹ̀! Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ, ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́ Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ, gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbékùn, nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́ nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ Ìwọ tí ń gbé Lẹ́bánónì, tí ó tẹ́ ìtẹ́ sí orí igi kédárì, ìwọ yóò ti kérora pẹ́ tó, nígbà tí ìrora bá dé bá ọ, ìrora bí i ti obìnrin tí ń rọbí! Dájúdájú bí èmi ti wà láàyè, ni Olúwa wí, Bí Jéhóíákínì ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀ Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì àti ọwọ́ àwọn ará Bábílónì Èmi ó fi ìwọ àti ìyá tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn, níbi tí a kò bí ẹnikẹ́ni nínú yín sí Níbẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì yóò kú sí Ẹ̀yin kì yóò padà sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin fẹ́ mọ́ láéláé Ǹjẹ́ Jéhóíákínì ẹni ẹ̀gàn yàtọ̀ sí ìkòkò òfìfo, ohun èlò tí ẹnìkan kò fẹ́ Èéṣe tí a fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sókè sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀ Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ! Báyìí ni Olúwa wí Kọ àkọsílẹ̀ ọkùnrin yìí sínú ìwé gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ, ẹni tí kì yóò ṣe rere ní ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí ọ̀kan nínú irú ọmọ rẹ̀ kì yóò ṣe rere, èyíkéyìí wọn kì yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì tàbí jọba ní Júdà mọ́ Ẹ̀ka Òtítọ́ Ègbé ni fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń tú agbo ẹran mi ká tí ó sì ń pa wọ́n run! ni Olúwa wí Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ ní ti àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń darí àwọn ènìyàn mi Nítorí tí ẹ̀yin tú agbo ẹran mi ká, tí ẹ lé wọn dànù tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ wọ́n wò Èmi yóò jẹ yín níyà nítorí nǹkan búburú tí ẹ ti ṣe, ni Olúwa wí Èmi Olúwa tìkálárami yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀ èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí síi, tí wọn ó sì pọ̀ síi Èmi ó wá olùṣọ́ àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù, ni Olúwa wí Ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dáfídì, Ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Júdà là, Ísírẹ́lì yóò sì máa gbé ní aláìléwu Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é Olúwa Òdodo wa Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí ènìyàn kì yóò tún wí pé, Dájúdájú Olúwa wà láàyè tí ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì Ṣùgbọ́n wọn yóò máa wí pé, Dájúdájú Olúwa ń bẹ tí ó mú irú ọmọ ilé Ísírẹ́lì wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti àwọn ilẹ̀ ibi tí mo tí lé wọn lọ, wọn ó sì gbé inú ilẹ̀ wọn Nípa ti àwọn wòlíì èké Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi, gbogbo egungun mi ni ó wárìrì Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn, bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa nítorí Olúwa àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀ Ilẹ̀ náà kún fún panṣágà ènìyàn nítorí ẹ̀gún ilẹ̀ náà gbẹ, àwọn kóríko orí aṣálẹ̀ ilẹ̀ náà rọ Àwọn wòlíì tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọ́n sì ń lo agbára wọn lọ́nà àìtọ́ Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwàbí Ọlọ́run kódà nínú Tẹ́ḿpìlì mi ni mo rí ìwà búburú wọn, ni Olúwa wí Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́, a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn, ní ọdún tí a jẹ wọ́n níyà, ni Olúwa wí Láàrin àwọn wòlíì Saáríà, Èmi rí ohun tí ń lé ni sá Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Báálì wọ́n sì mú Ísírẹ́lì ènìyàn mi sìnà Àti láàrin àwọn wòlíì Jérúsálẹ́mù, èmi ti rí ohun búburú Wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì ń ṣèké Wọ́n fún àwọn olùṣe búburú ní agbára, tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀ Gbogbo wọn dàbí Sódómù níwájú mi, àti àwọn ènìyàn olùgbé rẹ̀ bí Gòmórà Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run alágbára wí ní ti àwọn wòlíì Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò, wọn yóò mu omi májèlé nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jérúsálẹ́mù ni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, Ẹmá ṣe fi etí sí àṣọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlíì èké ń sọ fún un yín Wọ́n ń kún inú ọkàn yín pẹ̀lú ìrètí asán Wọ́n ń sọ ìran láti ọkàn ara wọn, kì í ṣe láti ẹnu Olúwa Wọ́n ń sọ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé, Olúwa ti wí pé Ẹ ó ní àlàáfíà, Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn tí ó rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀ pé, Kò sí ìpalára kan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín Ṣùgbọ́n èwo nínú wọn ni ó dúró nínú ìgbìmọ̀ Olúwa láti rí i tàbí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ Ta ni ó gbọ́ tí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ náà Wò ó, afẹ́fẹ́ Olúwa yóò tú jáde pẹ̀lú ìbínú àfẹ́yíká ìjì yóò fẹ́ sí orí àwọn olùṣe búburú Ìbínú Olúwa kì yóò yẹ̀ títí tí yóò sì fi mú èrò rẹ̀ ṣẹ, ní àìpẹ́ ọjọ́, yóò yé e yín yékéyéké Èmi kò rán àwọn wòlíì wọ̀nyí síbẹ̀ wọ́n lọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn Èmi kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀, síbẹ̀ wọ́n sọ àṣọtẹ́lẹ̀, Ṣùgbọ́n ìbáṣepọ̀ wọn dúró nínú ìgbìmọ̀ mi, wọn ì bá ti kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn ènìyàn mi Wọn ì bá ti wàásù ọ̀rọ̀ mi sí àwọn ènìyàn wọn ìbá ti yípadà kúrò nínú ọ̀nà àti ìṣe búburú wọn Ǹjẹ́ Ọlọ́run tòsí nìkan ni Èmi bí ni Olúwa wí, kì í sì í ṣe Ọlọ́run ọ̀nà jínjìn Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sá pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan, kí èmi má ba a rí ni Olúwa wí Ǹjẹ́ èmi kò há a kún ọ̀run àti ayé bí ni Olúwa wí Mo ti gbọ gbogbo ohun tí àwọn wòlíì èké tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi ń sọ Wọ́n sọ wí pé, Mo lá àlá! Mo lá àlá! Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀ṣíwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ ìtànjẹ ọkàn wọn Wọ́n rò wí pé àlá tí wọ́n ń sọ fún ara wọn yóò mú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé orúkọ mi nípa sísin òrìṣà Báálì Jẹ́ kí wòlíì tí ó bá lá àlá sọ àlá rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mí sọ ọ́ ní òtítọ́ Kí ni koríko gbígbẹ ní í ṣe nínú ọkà ni Olúwa wí Ọ̀rọ̀ mi kò há a dàbí iná ni Olúwa wí, àti bí òòlù irin tí ń fọ́ àpáta túútúú Nítorí náà, èmi lòdì sí àwọn wòlíì ni, Olúwa wí, Tí ń jí ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá lò lọ́dọ̀ ara wọn Bẹ́ẹ̀, ni Olúwa wí, Èmi lòdì sí àwọn wòlíì tí wọ́n lo ahọ́n wọn káàkiri, síbẹ̀ tí wọ́n ń ṣọ wí pé, Olúwa wí Nítòótọ́, mo lòdì sí àwọn tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àlá èké, ni Olúwa wí Wọ́n ń sọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń mú àwọn ènìyàn mi sìnà nípa onírúurú èké wọn, síbẹ̀ èmi kò rán wọn tàbí yàn wọ́n Wọn kò sì ran àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ bí ó ti wù kí ó kéré mọ, ni Olúwa wí Nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, tàbí wòlíì tàbí àlùfáà bá bi ọ́ léèrè wí pé, Kí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa Sọ fún wọn wí pé, ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ wo Èmi yóò pa yín tì ni Olúwa wí Bí wòlíì tàbí àlùfáà tàbí ẹnikẹ́ni bá sì gbà wí pé, Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa Èmi yóò fi ìyà jẹ ọkùnrin náà àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ Èyí ni ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ń sọ fún ọ̀rẹ́ àti ará ilé rẹ̀ Kí ni ìdáhùn Olúwa tàbí Kíni ohun tí Olúwa sọ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dárúkọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa mọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ oníkálùkù ènìyàn di ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀ Nítorí náà, ẹ̀yin ń yí ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run alágbára alààyè padà Èyí ni ohun tí ẹ̀yin ń sọ fún wòlíì Kí ni ìdáhùn Olúwa sí ọ́ tàbí Kí ni ohun tí Olúwa bá ọ sọ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ń sọ wí pé, Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa , èyí ni ohun tí Olúwa sọ Ó ń lo ọ̀rọ̀ yìí, Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa , bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo sọ fún un yín láti má ṣe gbà á, Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa Nítorí náà, Èmi yóò gbàgbé yín, bẹ́ẹ̀ ni n ó lé e yín kúrò níwájú mi pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè tí mo fi fún un yín àti àwọn baba yín Èmi yóò sì mú ìtìjú ayérayé wá sí orí yín, ìtìjú tí kò ní ní ìgbàgbé Agbọ̀n Èso Ọ̀pọ̀tọ́ Méjì Lẹ́yìn tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ti kó Jékóníà ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn oníṣọ̀nà àti oníṣẹ́ ọwọ́ ti Júdà lọ sí ìgbékùn láti Jérúsálẹ́mù lọ sí ilẹ̀ àjòjì Bábílónì tán Olúwa fi agbọ̀n èṣo ọ̀pọ̀tọ́ méjì hàn mí tí a gbé sí iwájú pẹpẹ Olúwa Agbọ̀n kan ni èṣo ọ̀pọ̀tọ́ tí ó dára bí èyí tí ó tètè pọ́n èkejì sì ní èṣo ọ̀pọ̀tọ́ tí ó burú rékọjá tí kò sì le è ṣe é jẹ Nígbà náà ni Olúwa bi mí pé, Kí ni ìwọ rí Jeremáyà Èṣo ọ̀pọ̀tọ́ Mo dáhùn Èyí tí ó dára dára púpọ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó burú burú rékọjá tí kò sì ṣe é jẹ Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Gẹ́gẹ́ bí àwọn èṣo ọ̀pọ̀tọ́ dáradára yìí ni Èmi yóò ka àwọn tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ àjòjì láti Júdà sí tí èmi rán jáde kúrò ní ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará kálídéà Ojú mi yóò máa ṣọ́ wọn lọ fún rere Èmi yóò gbé wọn ró, n kò ní já wọn lulẹ̀ Èmi yóò gbìn wọ́n, n kò sì ní fà wọ́n tu Èmi yóò fún wọn ní ọkàn láti mọ̀ mí pé, Èmi ni Olúwa Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi Èmi ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn nítorí pé wọn yóò padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn  Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí èṣo ọ̀pọ̀tọ́ tí kò dára, tí ó burú tí kò ṣe é jẹ, ni Olúwa wí, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe pẹ̀lú Ṣedekáyà Ọba Júdà, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn tí ó yẹ ní Jérúsálẹ́mù, yálà wọ́n wà lórí ilẹ̀ yìí tàbí wọ́n ń gbé Éjíbítì Èmi yóò sọ wọ́n di ìwọ̀sí àti ẹni ibi sí gbogbo ìjọba ayé, ẹni ẹ̀sín àti ẹni ẹ̀tẹ́, ẹni àbùkù àti ẹni èpè ní ibi gbogbo tí Èmi bá lé wọn sí Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn sí wọn, títí tí gbogbo wọn yóò parun lórí ilẹ̀ tí a fún wọn àti fún àwọn baba wọn   Aago Ìbínú Ọlọ́run Ọ̀rọ̀ sì tọ Jeremáyà wá nípa àwọn ènìyàn Júdà ní ọdún kẹrin Jéhóíákímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà, èyí tí ó jẹ́ ọdún kìn-ín-ní Nebukadinésárì Ọba Bábílónì Nítorí náà, Jeremáyà wòlíì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Júdà àti sí àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù Fún odidi ọdún mẹ́talélógún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kẹtàlá Jòsáyà, ọmọ Ámónì Ọba Júdà, títí di ọjọ́ yìí, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, mo sì ti sọ ọ́ fún un yín láti ìgbà dé ìgbà, àmọ́ ẹ̀yin kò fetí sílẹ̀ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì sí i yín láti ìgbà dé ìgbà, ẹ̀yin kò fetí sílẹ̀ Wọ́n sì wí pé, Ẹ yípadà olúkúlùkù yín kúrò ní inú ibi rẹ̀ àti ní ọ̀nà ibi rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì lè dúró ní ilẹ̀ tí Ọlọ́run fún un yín àti àwọn baba yín títí láéláé Má ṣe tọ àwọn Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n tàbí bọ wọ́n ẹ má ṣe mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ ti fi ọwọ́ yín ṣe Nígbà náà ni Èmi kò ní ṣe yín ní ibi Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi, ni Olúwa wí bẹ́ẹ̀ ni ẹ sì ti mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ fi ọwọ́ yín ṣe, ẹ sì ti mú ibi wá sórí ara yín Nítorí náà, Ọlọ́run alágbára sọ èyí Nítorí wí pé ẹ̀yin kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, ni Olúwa wí Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀ èdè àyíká rẹ̀ Èmi yóò pa wọ́n run pátapáta, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà Gbogbo orílẹ̀ èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀ èdè yìí yóò sì sìn ní Bábílónì ní àádọ́rin ọdún Ṣùgbọ́n, nígbà tí àádọ́rin ọdún náà bá pé Èmi yóò fi ìyà jẹ Ọba Bábílónì àti orílẹ̀ èdè rẹ, ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ni Olúwa wí bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ ani gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè Àwọn fúnra wọn yóò sì sin orílẹ̀ èdè púpọ̀ àti àwọn Ọba ńlá Èmi yóò sì sán fún oníkálukú gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí fún mi Gba aago yìí ní ọwọ́ mí tí ó kún fún ọtí wáìnì ìbínú mi, kí o sì mú gbogbo orílẹ̀ èdè ti mo rán ọ sí mu ún Nígbà tí wọ́n bá mu ún, wọn yóò ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n di aṣiwèrè nítorí idà tí mo fi ránṣẹ́ sí àárin wọn Mo sì gba aago náà lọ́wọ́ Olúwa , bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó rán mi sí mu ún Jérúsálẹ́mù àti àwọn ìlú Júdà, àwọn Ọba wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ wọn, láti sọ wọ́n di ohun ìparun, ohun ẹ̀rù, ẹ̀sìn àti ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rí lónìí yìí Fáráò Ọba Éjíbítì, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn aláṣẹ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Àti gbogbo àwọn ènìyàn àjòjì tí ó wà níbẹ̀ gbogbo àwọn Ọba Húsì, gbogbo àwọn Ọba Fílístínì, gbogbo àwọn ti Áṣíkélónì, Gásà, Ékírónì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kù sí Áṣídódì Édómù, Móábù àti Ámónì Gbogbo àwọn Ọba Tirè àti Sídónì gbogbo àwọn Ọba erékùṣù wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ìkọjá òkun Dédánì, Témà, Búsì àti gbogbo àwọn tí ń gbé lọ́nà jínjìn réré Gbogbo àwọn Ọba Árábíà àti àwọn Ọba àwọn àjòjì ènìyàn tí ń gbé inú ihà Gbogbo àwọn Ọba Símírì, Élámù àti Mídíà Àti gbogbo àwọn Ọba àríwá ní tòsí àti lọ́nà jínjìn, ẹnìkìn-ín-ní lẹ́yìn ẹnìkejì gbogbo àwọn ìjọba lórí orílẹ̀ ayé Àti gbogbo wọn, Ọba Ṣéṣákì náà yóò sì mu Nígbà náà, sọ fún wọn Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì wí Mu, kí o sì mu amuyó kí o sì bì, bẹ́ẹ̀ ni kí o sì ṣubú láì dìde mọ́ nítorí idà tí n ó rán sí àárin yín Ṣùgbọ́n bí wọ́n ba kọ̀ láti gba aago náà ní ọwọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, sọ fún wọn pé, Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára sọ Ẹyin gbọdọ̀ mu ún! Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀ èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi ǹjẹ́ yóò há a lè lọ láìjìyà Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ Nísinsinyìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn  Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá, yóò sì bú àrá kíkankíkan sí ilẹ̀ náà Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé, nítorí pé Olúwa yóò mú ìjà wá sí orí àwọn orílẹ̀ èdè náà, yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn, yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,  ni Olúwa wí Èyí ni ohun tí Olúwa ọmọ ogun wí Wò ó! Ibi ń tànkálẹ̀ láti orílẹ̀ èdè kan sí òmíràn Ìjì ńlá yóò sì ru sókè láti òpin ayé Nígbà náà, àwọn tí Olúwa ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn A kì yóò sọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀ Ké, kí ẹ sì pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùsọ́ àgùntàn, ẹ yí nínú eruku, ẹ̀yin olùdarí agbo ẹran, nítorí pé ọjọ́ àti pa yín ti dé, ẹ̀yin ó sì ṣubú bí ohun èlò iyebíye Àwọn olùsọ́ àgùntàn kì yóò ríbi sálọ kì yóò sì sí àsálà fún olórí agbo ẹran Gbọ́ igbe àwọn olùsọ́ àgùntàn, àti ìpohùnréré ẹkún àwọn olórí agbo ẹran nítorí pé Olúwa ń pa pápá oko tútù wọn run Pápá oko tútù yóò di asán nítorí ìbínú ńlá Olúwa Gẹ́gẹ́ bí kìnnìún yóò fi ibùba rẹ̀ sílẹ̀, ilẹ̀ wọn yóò sì di ahoro, nítorí idà àwọn anínilára, àti nítorí ìbínú ńlá Olúwa Wọ́n Fi Ikú Halẹ̀ Mọ́ Jeremáyà Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Ọba Jehóáíkímù ọmọ Jòsáyà tí ń ṣe Ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Èyí ni ohun tí Olúwa wí Dúró ní àgbàlà ilé Olúwa , kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Júdà tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé Olúwa sọ gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún ọ má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọọkan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n Sọ fún wọn wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé síwájú yín Àti tí ẹ kò bá fetísí àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò fetí sílẹ̀ Mà á jẹ́ kí ilé yìí dàbí sílò, n ó sọ ìlú yìí kí ó dàbí ìfibú fún gbogbo àgbáyé   Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremáyà tí ó sọ ní ilé Olúwa Ṣùgbọ́n ní kété tí Jeremáyà ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí Olúwa pa láṣẹ láti sọ àwọn àlùfáà, àti gbogbo ènìyàn dì í mú, wọ́n sì wí pé, Kíkú ni ìwọ yóò kú! Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àṣọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa pé, ilé yìí yóò dàbí ṣílò, orílẹ̀ èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremáyà nínú ilé Olúwa Nígbà tí àwọn aláṣẹ Júdà gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, wọ́n lọ láti ààfin sí ilé Olúwa , wọ́n sì mú àyè wọn, wọ́n jòkòó ní ẹnu ọ̀nà tuntun ilé Olúwa Àwọn àlùfáà àwọn wòlíì sọ fún àwọn aláṣẹ àti gbogbo ènìyàn pé, Arákùnrin yìí gbọdọ̀ gba ìdájọ́ ikú nítorí pé ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ lórí ìlú yìí bí ẹ̀yin ti fi etí yín gbọ́! Nígbà náà ni Jeremáyà sọ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn wí pé Olúwa rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé yìí àti ìlú yìí, gbogbo ohun tí ẹ ti gbọ́ Nísinsìnyìí, tún ọ̀nà rẹ ṣe àti ìṣe rẹ, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín Olúwa yóò yí ọkàn rẹ̀ padà, kò sì ní mú ohun gbogbo tí ó ti sọ jáde ní búburú ṣẹ lórí yín Bí ó bá ṣe tèmi ni, èmi wà ní ọwọ́ yín, ẹ ṣe ohun tí ẹ̀yin bá rò pé ó dára, tí ó sì tọ́ lójú yín fún mi Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí orílẹ̀ èdè yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀ nítorí pé nítòótọ́ ni Olúwa ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ ogun Lára àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà sì sún ṣíwájú, wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, Míkà ti Mórásì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Heṣekáyà Ọba Júdà Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Júdà pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí  A ó sì fa Síónì tu bí oko Jérúsálẹ́mù yóò di òkítì àlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ibi gíga igbó Ǹjẹ́ Heṣekáyà Ọba Júdà tàbí ẹnikẹ́ni ní Júdà pa á bí Ǹjẹ́ Heṣekáyà kò bẹ̀rù Olúwa tí ó sì wá ojúrere rẹ̀ Ǹjẹ́ Olúwa kò há a sì yí ìpinnu rẹ̀ padà, tí kò sì mú ibi tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ yẹ̀ kúrò lórí wọn Ibi ni a fẹ́ mú wá sórí ara wa yìí Áhíkámù ọmọ Sáfánì ń bẹ pẹ̀lú Jeremáyà, wọn kò sì fi í lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti pa á Júdà Yóò Sin Nebukadinésárì Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Sedekáyà ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Èyí ni ohun tí Olúwa wí Ṣe ìjárá àti àjàgà fún ara rẹ, kí o sì fi wé ọrùn rẹ Kí o rán ọ̀rọ̀ sí Ọba ti Édómù, Móábù, Ámónì, Tírè àti Sídónì láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jérúsálẹ́mù sọ́dọ̀ Sedekáyà Ọba Júdà Kí o sì pàṣẹ fún wọn láti wí fún àwọn olúwa wọn pé, Èyí ni ohun tí Olúwa ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Sọ èyí fún àwọn olúwa rẹ Pẹ̀lú agbára ńlá mi àti ọwọ́ nínà mi ni Èmi dá ayé, ènìyàn àti ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Mo sì fún ẹni tí ó wu ọkàn mi Nísinsìn yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀ èdè rẹ fún Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ìránṣẹ́ mi Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀ Gbogbo orílẹ̀ èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè àti àwọn Ọba ńlá ni yóò tẹríba fún   Àmọ́ tí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀ Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀ èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, ni Olúwa wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀ Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tabi àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, Èyin kò ní sin Ọba Bábílónì Wọ́n ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún un yín èyí tí yóò mú u yín jìnnà réré kúrò ní ilẹ̀ yín kí Èmi kí ó lè lé yín jáde, kí ẹ̀yin ó sì ṣègbé Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀ èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà Ọba Bábílónì, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀ èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí    Èmi sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Sedekáyà Ọba Júdà wí pé Tẹ orí rẹ ba lábẹ́ àjàgà Ọba Bábílónì, sìn ín ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ yóò sì yè Kí ló dé tí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, èyí tí Olúwa fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè tí kò bá sin Ọba Bábílónì Ẹ má ṣe fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ó ń sọ wí pé, Ẹ̀yin kò ní sin Ọba Bábílónì, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ eké ni wọ́n ń sọ fún un yín Èmi kò rán wọn ni Olúwa wí Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi Nítorí náà, Èmi yóò lé wọn, wọn yóò sì ṣègbé, ẹ̀yin pẹ̀lú àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín   Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa sọ Ẹ má ṣe fetí sí nǹkan tí àwọn wòlíì ń sọ pé, Láìpẹ́ ohun èlò ilé Olúwa ni a ó kó padà láti Bábílónì, àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ Ẹ má tẹ́tí sí wọn Má ṣe tẹ́tí sí wọn, ẹ máa sin Ọba Bábílónì, ẹ̀yin yóò sì yè Èéṣe tí ẹ̀yin yóò fi di ìdíbàjẹ́ Tí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ Olúwa , jẹ́ kí wọ́n bẹ Olúwa kí a má ṣe kó ohun èlò tí ó kù ní ilé Júdà àti Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì Nítorí pé, èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa àwọn opó, omi òkun níti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti níti ohun èlò ìyókù tí ó kù ní orílẹ̀ èdè náà Èyí tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì kò kó lọ nígbà tí ó mú Jéhóíákímù Ọba Júdà lọ sí ìgbèkùn láti Jérúsálẹ̀mù lọ sí Bábílónì, pẹ̀lú àwọn ọlọ́lá Júdà àti Jérúsálẹ́mù Lóòótọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí nípa àwọn ohun ìṣúra tí ó ṣẹ́kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin Ọba Júdà àti ní Jérúsálẹ́mù A ó mú wọn lọ sí ilẹ̀ Bábílónì, ní ibẹ̀ ni wọn ó sì wà títí di ìgbà tí mo bá padà, èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa Lẹ́yìn èyí, mà á mú wọn padà, Èmi yóò sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ ní ibí yìí   Hananáyà Wòlíì Èké Ní oṣù karùn ún ní ọdún kan náà, ọdún kẹrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba Sedekáyà Ọba Júdà, wòlíì Hananáyà ọmọ Ásúrì, tí ó wá láti Gíbíónì, sọ fún mi ní ilé Olúwa tí ó wà ní iwájú àwọn àlùfáà àti gbogbo ènìyàn Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Èmi yóò mú àjàgà Ọba Bábílónì rọrùn Láàrin ọdún méjì, mà á mú gbogbo ohun èlò tí Ọba Nebukadinésárì Ọba Bábílónì kó kúrò ní ilé Olúwa tí ó sì kó lọ sí Bábílónì padà wá Èmi á tún mú àyè Jéhóíákínì ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti Júdà ní Bábílónì, èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa pé, àjàgà yín láti ọwọ́ Ọba Bábílónì yóò rọrùn   Wòlíì Jeremáyà fún wòlíì Hananáyà lésì ní iwájú ọmọ àlùfáà àti àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ilé Olúwa Ó sọ wí pé, Àmín! Kí Olúwa ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Olúwa ó mú àwíṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun èlò ilé Olúwa àti gbogbo àwọn aṣàtìpó padà sí ilẹ̀ Bábílónì Nísinsìnyìí, tẹ́tí sí àwọn ohun tí mo sọ fún gbígbọ́ àti fún gbígbọ́ gbogbo ènìyàn Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn wòlíì tí ó ṣáájú rẹ àti èmi ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ibi àti àjàkálẹ̀ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè Ṣùgbọ́n, àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà ni a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì olótítọ́ tí Olúwa rán, tí àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ bá wá sí ìmúṣẹ Wòlíì Hananáyà gbé àjàgà ọrùn wòlíì Jeremáyà kúrò, ó sì fọ́ ọ Ó sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí Bákan náà ni mà á fọ́ àjàgà ọrùn Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì láàrin ọdún méjì   Jeremáyà sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananáyà ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremáyà wí pé Lọ sọ fún Hananáyà, Èyí ni ohun tí Olúwa wí Ìwọ ti wó àjàgà onígi, ṣùgbọ́n ní àyè wọn, wà á bá àjàgà onírin Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí mà á fi àjàgà onírin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀ èdè láti lè máa sin Nebukadinésárì ti Bábílónì, àti pé gbogbo yín ni ẹ̀ ó máa sìn ín Mà á tún fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko búburú   Wòlíì Jeremáyà sọ fún Hananáyà wòlíì pé, Tẹ́tí, Hananáyà! Olúwa ti rán ọ, síbẹ̀, o rọ orílẹ̀ èdè yìí láti gba irọ́ gbọ́ Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí Mo ṣetán láti mú ọ kúrò nínú ayé, ní ọdún yìí ni ìwọ yóò kú nítorí o ti wàásù ọ̀tẹ̀ sí Olúwa   Ní oṣù keje ọdún yìí ni Hananáyà wòlíì kú Lẹ́tà Sí Àwọn Aṣàtìpó Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremáyà fi ránṣẹ́ láti Jérúsálẹ́mù sí àwọn tí ó yè nínú àwọn aṣàtìpó àti àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn Nebukadinésárì tí wọ́n ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù ní Bábílónì Èyí ṣẹlẹ̀ ní ẹ̀yìn ìṣèjọba Jéhóíákímù àti ayaba àti ìwẹ̀fà pẹ̀lú àwọn olórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù, àwọn gbẹ́nà gbẹ́nà àti àwọn olùyàwòrán tí wọ́n lọ ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù Ó fi lẹ́tà náà rán Élásà ọmọ Híkáyà ti Ṣédà Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí mo kó lọ ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù ní Bábílónì Ó kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èṣo ohun ọ̀gbìn oko yín Ẹ ṣe ìgbéyàwó, kí ẹ sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ẹ gbé ìyàwó fún àwọn ọmọkùnrin yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin yín fọ́kọ Kí àwọn náà lè ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ẹ máa pọ̀ síi ní iye, ẹ kò gbọdọ̀ dínkù ní iye níbẹ̀ rárá Bákan náà, ẹ máa wá àlàáfíà àti ire ilẹ̀, èyí tí mo kó yín lọ láti ṣe àtìpó Ẹ gbàdúrà sí Olúwa fún ire ilẹ̀ náà nítorí pé bí ó bá dára fún ilẹ̀ náà, yóò dára fún ẹ̀yin pẹ̀lú Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Ẹ má ṣe gbà kí àwọn wòlíì èké àti àwọn aláfọ̀ṣẹ àárin yín tàn yín jẹ Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí àlá, èyí tí ẹ gbà wọ́n níyànjú láti lá Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín lórúkọ mi Èmi kò rán wọn níṣẹ́, ni Olúwa wí Báyìí ni Olúwa wí Nígbà tí ẹ bá lo àádọ́rin ọdún pé ní Bábílónì, èmi yóò tọ̀ yín wá láti ṣe àmúṣẹ ìlérí ńlá mi fún un yín, àní láti kó o yín padà sí Jérúsálẹ́mù Nítorí mo mọ ète tí mo ní fún un yín, ni Olúwa wí, Ète láti mú yín lọ́rọ̀ láìpa yín lára, ète láti fún un yín ní ìrètí ọjọ́ iwájú Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín Ẹ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi ẹ̀yin yóò rí mi ni Olúwa Ọlọ́run wí Èmi yóò sì mú yín kúrò ní ìgbékùn Èmi yóò ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀ èdè àti ibi gbogbo tí mo ti lé yín jáde Èmi yóò sì kó yín padà sí Jérúsálẹ́mù ibi tí mo ti kó jáde lọ sí ilé àtìpó Ẹ lè sọ pé, Olúwa ti gbé àwọn wòlíì dìde fún wa ní Bábílónì Ṣùgbọ́n èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa nípa Ọba tó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù ní ìlú náà àní àwọn ènìyàn ìlú yín tí kò lọ sí ilé àtìpó pẹ̀lú yín Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run alágbára wí pé Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn sí wọn Èmi yóò sọ wọ́n dà bí ọ̀pọ̀tọ́ búburú tí kò ṣe é jẹ Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn ni Èmi yóò fi lé wọn Èmi yóò sì sọ wọ́n di ìríra lójú gbogbo ìjọba ayé, àti ohun ẹ̀gún àti ẹ̀rù ohun ẹ̀gbin àti ohun ẹ̀dùn láàrin gbogbo orílẹ̀ èdè ayé Nítorí wọ́n kọ̀ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ni Olúwa Ọlọ́run wí Ọ̀rọ̀ tí mo tún ti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sọ ni ẹ̀yin tí ń ṣe àtìpó kò gbọ́ ni Olúwa Ọlọ́run wí Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin àtìpó, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa , ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run sọ nípa Áhábù ọmọ Kóláháyà àti nípa Sedekáyà ọmọ Máséà tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún un yín lórúkọ mi Èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lọ́wọ́ Òun yóò sì gba ẹ̀mí wọn ní ìṣẹ́jú yìí gan an Nítorí ti wọn, ègún yìí yóò ran gbogbo àwọn àtìpó tó wà ní ilẹ̀ Bábílónì láti Júdà Ọlọ́run yóò ṣe yín bí i Sedekáyà àti Áhábù tí Ọba Bábílónì dáná sun Nítorí wọ́n ti ṣe ibi ní ilé Ísírẹ́lì, wọ́n ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ìyàwó aládùúgbò wọn, àti ní orúkọ mi ni wọ́n ti ṣe èké, èyí tí èmi kò rán wọn láti ṣe Ṣùgbọ́n, Èmi mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí sí i, ni Olúwa wí Wí fún Ṣemáyà tí í ṣe Neelamíyà pé, Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì wí Ìwọ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù sí Sefanáyà ọmọ Mááséà tí í ṣe àlùfáà ní orúkọ mi ó sì sọ fún Sefanáyà wí pé, Olúwa ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jéhóíádà láti máa jẹ́ alákóso ilé Olúwa , kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin Nítorí náà, èéṣe tí o kò fi bá Jeremáyà ará Ánátótì wí Ẹni tí ó ń dúró bí i wòlíì láàrin yín Ó ti rán iṣẹ́ yìí sí wa ni Bábílónì wí pé, àtìpó náà yóò pẹ́ kí ó tó parí, nítorí náà, ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èṣo ohun ọ̀gbìn oko yín   Sefanáyà àlùfáà ka lẹ́tà náà sí etí ìgbọ́ Jérúsálẹ́mù tí í ṣe wòlíì Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé, Rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo àwọn àtìpó Èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa Ṣemáyà àti Neelamaiti Nítorí pé Semaíà ti sọ tẹ́lẹ̀ fún un yín, súgbọ́n èmi kò ran an, tí òun sì ń mú u yín gbẹ́kẹ̀lé èké Nítorí pé, Èmi kò rán Ṣemáyà ní àṣọtẹ́lẹ̀ tí ó sọ fún un yín, ó sì ti mú kí ẹ gba àṣọtẹ́lẹ̀ èké gbọ́ Èmi yóò fi ìyà jẹ Ṣemáyà àti àwọn ọmọ rẹ̀ Kò sí ẹni tí yóò ṣẹ́kù nínú àwọn ìran rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò rí àwọn ohun rere tí èmi yóò ṣe fún àwọn ènìyàn mi, nítorí ó ti kéde ìṣọ̀tẹ̀ sí mi, ni Olúwa wí   Ísírẹ́lì Aláìsòótọ́ Bí ọkùnrin kan bá sì kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tí obìnrin náà sì lọ fẹ́ ọkọ mìíràn, ǹjẹ́ ọkùnrin náà tún lè tọ̀ ọ́ wá Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kò ní di aláìmọ́ bí Ṣùgbọ́n ìwọ ti gbé pẹ̀lú onírúurú panṣágà gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́, ṣé ìwọ yóò tún padà sọ́dọ̀ mi bí ni Olúwa wí Gbé ojú rẹ sí ibi gíga aláìléso kí o sì wò ó ibi kan ha wà tí a kò ti fi agbára mú ọ Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́, o jókòó bí i àwọn alárìnkiri nínú ihà O ti ba ilẹ̀ náà jẹ́ pẹ̀lú ìwà panṣágà àti ìwà búburú rẹ Nítorí náà, a ti fa ọ̀wàrà òjò sẹ́yìn, kò sì sí òjò àrọ̀kúrò Síbẹ̀ ìwọ ní ojú líle ti panṣágà, ìwọ sì kọ̀ láti ní ìtìjú Ǹjẹ́ ìwọ kò há a pè mí láìpẹ́ yìí pé, Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi Ìwọ yóò ha máa bínú títí Ìbínú rẹ yóò ha máa lọ títí láé Báyìí ni o ṣe ń sọ̀rọ̀ ìwọ ń ṣe gbogbo ibi tí o le ṣe Ní àkókò ìjọba Jòsáyà Ọba, Olúwa wí fún mi pé, Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ti ṣe Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀ Mo rò pé nígbà tí wọ́n ti ṣe èyí wọn yóò padà, wọn kò padà, Júdà aláìgbàgbọ́ arábìnrin rẹ̀ náà sì rí i Mo fún Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, mo sì ké wọn kúrò nítorí gbogbo àgbèrè wọn Ṣíbẹ̀ mo rí pé Júdà tí ó jẹ́ arábìnrin rẹ̀ kò bẹ̀rù, òun náà sì jáde lọ láti lọ ṣe àgbèrè Nítorí ìwà èérí Ísírẹ́lì kò jọ ọ́ lójú, ó ti ba ilẹ̀ jẹ́, ó sì ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú òkúta àti igi Látàrí gbogbo nǹkan wọ̀nyí Júdà arábìnrin rẹ̀ aláìgbàgbọ́ kò padà tọ̀ mí wá pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, bí kò ṣe nípa fífarahàn bí olótìtọ́, ni Olúwa wí Olúwa wí fún mi pé, Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Júdà tí ó ní Ìgbàgbọ́ lọ Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá  Yípadà, Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́, ni Olúwa wí Ojú mi kì yóò le sí yín mọ́, nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni Olúwa wí Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ, o ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, o ti wá ojú rere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì lábẹ́ gbogbo igikígi, tí ó tẹ́wọ́, o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu,  ni Olúwa wí Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́, ni Olúwa wí, nítorí èmi ni ọkọ rẹ Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà Èmi ó sì mú ọ wá sí Síónì Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́ àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀ Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà, ni Olúwa wí, àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, Àpótí ẹ̀rí Olúwa kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́ Ní ìgbà náà, wọn yóò pe Jérúsálẹ́mù ní ìtẹ́ Olúwa gbogbo orílẹ̀ èdè yóò péjọ sí Jérúsálẹ́mù láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ Olúwa , wọn kì yóò sì tún tẹ̀lé àyà líle burúkú wọn mọ́ Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Júdà yóò darapọ̀ mọ́ ilé Ísírẹ́lì Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní Èmi fúnra mi sọ wí pé,  Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó, kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrin kí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní Baba mi o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi Ìwọ ilé Ísírẹ́lì ni Olúwa wí A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga, ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po, wọ́n sì ti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́, Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run wa Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrùkèrudò tí ó wà ní àwọn orí òkè kékèké àti àwọn òkè gíga Nítòótọ́, nínú Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà Ísírẹ́lì wà Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú ti pa èso iṣẹ́ àwọn baba wa, ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn, ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa, kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀ A ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, àwa àti àwọn baba wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní a kò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run wa Ìmúpadà Sípò Ísírẹ́lì Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, wí pé Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, pé Ìwọ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ sínú ìwé kan Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní, ni Olúwa Ọlọ́run wí Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Ísírẹ́lì àti Júdà Èyí ni ohun tí Olúwa wí  Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì láìṣe igbe àlàáfíà Béèrè kí o sì rí Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí, tí ojú gbogbo wọn sì fàro fún ìrora Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó! Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀, Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jákọ́bù ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà  Ní ọjọ́ náà, Olúwa wí pé Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn, Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù Àwọn alejo kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́ Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dáfídì gẹ́gẹ́ bí Ọba wọn, ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn  Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi, má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì, ni Olúwa wí Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jínjìn wá, àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn Jákọ́bù yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà, kò sì sí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́ Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́, ni Olúwa wí Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀ èdè run, nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká, síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátapáta Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà Èyí ni ohun tí Olúwa wí  Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn, bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn Kò sí ẹnìkan tí yóò bẹ̀bẹ̀ fún àìṣedéédéé yín, kò sí ètùtù fún ọgbẹ́ yín, a kò sì mú yín láradá Gbogbo àwọn ìbátan yín ló ti gbàgbé yín, wọn kò sì náání yín mọ́ pẹ̀lú Mo ti nà yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀ta yín yóò ti nà yín mo sì bá a yín wí gẹ́gẹ́ bí ìkà nítorí tí ẹ̀bi yín pọ̀ púpọ̀, ẹ̀ṣẹ̀ yín kò sì lóǹkà Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín, ìrora yín èyí tí kò ní oògùn Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó ga ni mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá, àní gbogbo àwọn ọ̀ta yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjòjì gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́ Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín, n ó sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn, ni Olúwa wí, nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri Síónì tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí Èyí ni ohun tí Olúwa wí  Èmi yóò dá gbogbo ire àgọ́ Jákọ́bù padà, èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀ ìlú náà yóò sì di títúnṣe tí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀ Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àti ìyìn yóò sì ti máa jáde Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀, wọn kì yóò sì dínkù ní iye, Èmi yóò fi ọlá fún wọn, wọn kò sì ní di ẹni àbùkù Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanì níwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára, ni èmi yóò fìyà jẹ Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn, Ọba wọn yóò dìde láti àárin wọn Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi, nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jìn láti súnmọ́ mi Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín,  ni Olúwa wí Wò ó, ìbínú Ọlọ́run yóò tú jáde, ìjì líle yóò sì sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn búburú Ìbínú ńlá Ọlọ́run kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ìkà títí yóò fi mú èròǹgbà ọkàn rẹ̀ ṣẹ Ní àìpẹ́ ọjọ́, òye rẹ̀ yóò yé e yín Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Ísírẹ́lì, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi, ni Olúwa wí Èyí ni ohun tí Olúwa wí Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idà yóò rí ojúrere Olúwa ní aṣálẹ̀, Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Ísírẹ́lì Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín, Èmi yóò tún gbé e yín sókè, àní a ó tún gbé e yín ró iwọ wúndíá ilẹ̀ Ísírẹ́lì Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé, ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀ Ẹ ó tún dá oko ní orí òkè Saáríà àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa gbádùn èso oko wọn Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde lórí òkè Éfráímù wí pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Síónì, ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa   Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé Ẹ fi ayọ̀ Kọrin sí Jákọ́bù ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀ èdè gbogbo Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé, Olúwa , gba àwọn ènìyàn rẹ là àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Ísírẹ́lì Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ, aboyún àti obìnrin tí ń rọbí, ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún, wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú, nítorí èmi ni baba Ísírẹ́lì, Éfúráímù sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin orílẹ̀ èdè ẹ kéde rẹ̀ ní erékùsù jínjìn Ẹni tí ó bá tú Ísírẹ́lì ká yóò kójọ, yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn Nítorí Olúwa ti tú Jákọ́bù sílẹ̀, o sì ràá padà ní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Síónì wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore Olúwa Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin, ìkorò kò ní bá wọn mọ́ Àwọn wúndíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀, dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ Èmi ó tẹ́ àwọn àlùfáà lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mi yóò sì kún fún oore mi, ni Olúwa wí Èyí ni ohun tí Olúwa wí A gbọ́ ohùn kan ní Rámà tí ń sọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò Rákélì ń sọkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ kò gbà kí wọ́n tu òun nínú, nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́ Báyìí ni Olúwa wí Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkún àti ojú rẹ nínú omijé nítorí a ó fi èrè sí isẹ́ rẹ, ni Olúwa wí Wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá Nítorí ìrètí wà fún ọjọ́ iwájú rẹ, ni Olúwa wí Àwọn ọmọ rẹ yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Éfúráímù wí pé, Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́ èmi sì ti gbọ́ ìbáwí Ràmípadà, Èmi yóò sì yípadà, nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run mi Lẹ́yìn tí mo ti ronúpìwàdà, èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi, lẹ́yìn tí mo ti mọ̀, èmi lu àyà mi Ojú tì mí, mo sì dààmú nítorí èmi gba èrè ẹ̀gàn ìgbà èwe mi Éfúráímù kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára tí inú mi dùn sí bí Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó, síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀ Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un, èmi káàánú gidigidi fún un, ni Olúwa wí Gbé àmì ojú ọ̀nà dìde, ṣe atọ́nà àmì, kíyèsí pópónà rélùwéè ojú ọ̀nà tí ó ń gbà Yípadà ìwọ wúndíá Ísírẹ́lì, padà sí àwọn ìlú rẹ Ìwọ yóò ti sìnà pẹ́ tó, ìwọ aláìsòótọ́ ọmọbìnrin Olúwa yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀, ọmọbìnrin yóò yí ọkùnrin kan ká Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Júdà àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan síi wí pé, Olúwa bùkún fún ọ, ìwọ tí ń gbé nínú òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́ Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Júdà àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀ bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káànú lọ́rùn Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, nígbà tí èmi yóò gbin ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn, ni Olúwa wí Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ènìyàn kò ní sọ mọ́ pé  Àwọn baba ti jẹ èṣo kíkan àti pé ẹyín kan àwọn ọmọdé Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èṣo kíkan ni eyín yóò kan Ìgbà kan ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí Èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun Kò ní dàbí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́, tí mo mú wọn jáde ní Éjíbítì nítorí wọ́n da májẹ̀mú mi Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn, ni Olúwa wí Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìgbà náà, ni Olúwa wí pé Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn, èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn Èmi ó jẹ́ Olúwa wọn àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀ tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, Ẹ mọ Olúwa , nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí láti ẹni kékeré wọn títídé ẹni ńlá, ni Olúwa wí Nítorí èmi ó dárí àìṣedédé wọn jì, èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́ Èyí ni ohun tí Olúwa wí ẹni tí ó mú oòrùn tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀ ràn ní òru tí ó rú omi òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí Ìjì rẹ̀ fi ń hó Olúwa àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀ Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi, ni Olúwa wí Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò dẹ́kun láti jẹ́ orílẹ̀ èdè níwájú mi láéláé Èyí ni ohun tí Olúwa wí Àyàfi tí a bá lé àwọn ọ̀run lókè tí ìpìlẹ̀ ayé sì di àwárí ní ìṣàlẹ̀, ni èmi yóò kọ àwọn Ísírẹ́lì nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe, ni Olúwa wí Ọjọ́ náà ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí wọn yóò tún ìlú yìí kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hánánélì dé igun ẹnubodè Okùn ìwọ̀n yóò sì nà jáde láti ibi gígùn lọ sí òkè Gárébì yóò sì lọ sí Góà Gbogbo àfonífojì níbi tí wọ́n ń da òkú àti eérú sí, àti gbogbo àfonífojì odò Kídírónì ní ìhà ìlà oòrùn títí dé igun ẹnubodè ẹṣin yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa A kì yóò fa ìlú náà tu tàbí kí a wó o palẹ̀ Jeremáyà Ra Pápá Kan Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọdún kẹwàá sédékáyà Ọba Júdà, èyí tí ó jẹ́ ọdún kejìdínlógún ti Nebukadinésárì Àwọn ogun Ọba Bábílónì ìgbà náà há Jérúsálẹ́mù mọ́ A sì ṣé wòlíì Jeremáyà mọ́ inú túbú tí wọ́n ń sọ́ ní àgbàlá ilé Ọba Júdà Nítorí Sedekáyà Ọba Júdà ti há a mọ́lé síbẹ̀ pé, Kí ló dé tí ìwọ fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ báyẹn Tí o sì wí pé, Báyìí ni Olúwa wí Èmi ń bọ̀ wá fi ìlú yìí fún Ọba Bábílónì, tí yóò sì gbà á Sedekáyà Ọba Júdà kò lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn Kálídéà, ṣùgbọ́n à ó mú fún Ọba Bábílónì, yóò sì bá sọ̀rọ̀ ní ojúkojú yóò sì rí pẹ̀lú ojú rẹ̀ Yóò mú Sedekáyà lọ sí Bábílónì tí yóò wà títí èmi yóò fi bẹ̀ ọ́ wò ni Olúwa wí Tí ẹ̀yin bá bá àwọn ará Kálídéà jà, ẹ̀yin kì yóò borí wọn   Jeremáyà wí pé, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé Hánámélì ọmọkùnrin Sálúmù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò tọ̀ ọ́ wá pé, Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó sún mọ́ wọn, ẹ̀tọ́ àti ìṣe rẹ ní láti rà á Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ, ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì tí ó wà ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì, èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni èyí Bẹ́ẹ̀ ni èmi ra pápá náà ní Ánátótì láti ọwọ́ Hánámélì ọmọ ẹ̀gbọ́n mi Ó sì wọn ìwọn ṣékélì àti fàdákà mẹ́tadínlógún fún un Mo fọwọ́ sínú ìwé, mo sì dì í pa Mo pe ẹlẹ́rìí síi, mo sì wọn fàdákà náà lórí òṣùwọ̀n Mo mú ìwé tí mo fi rà á, èyí tí a di pa nípa àṣẹ àti òfin wa, àti èyí tí a kò lẹ̀ Èmi sì fi èyí fún Bárúkì ọmọkùnrin ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ti fi ọwọ́ sí ìwé àti ní ojú àwọn Júù gbogbo tí wọ́n jókòó ní àgbàlá túbú Ní ojú wọn ni èmi ti pàṣẹ fún Bárúkì pé Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí mú àwọn ìwé tí a fi rà á wọ̀nyí, àti èyí tí a lẹ̀ àti èyí tí a kò lẹ̀, kí o wá gbé wọn sínú ìkòkò amọ̀, kí wọn ó lè wà ní ọjọ́ púpọ̀ Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí àwọn ilẹ̀, pápá àti ọgbà àjàrà ni à ó tún rà padà nílẹ̀ yìí Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé rírà náà fún Bárúkì ọmọkùnrin Néráyà, mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé Áà! Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbogbo, ìwọ tí o dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú títóbi agbára rẹ àti gbogbo ọ̀rọ̀ apá rẹ Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ láti ṣe O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹ̀gbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn Ọlọ́rùn títóbi àti alágbára, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ Títóbi ni iṣẹ́ rẹ, agbára sì ni ìṣe rẹ Ojú rẹ sí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọkùnrin, ó sì fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti ìwà rẹ̀ O ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá ní Éjíbítì O sì ń ṣe é títí di òní ní Ísírẹ́lì àti lára ọmọ ènìyàn tí ó sì ti gba òkìkí tí ó jẹ́ tìrẹ O kó àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ jáde láti Éjíbítì pẹ̀lú àmì àti ìyanu nínú ọwọ́ agbára àti nína apá rẹ pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá Ìwọ fún wọn nílẹ̀ yìí, èyí tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ Wọn kò ṣe ohun tí o paláṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn Wò ó, bí àwọn ìdọ̀tí ṣe korájọ láti gba ìlú Nítorí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, sì fi ìlú lé ọwọ́ àwọn ará Kálídéà tí ń gbógun tì wọ́n Ohun tí ìwọ sọ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i Ṣíbẹ̀ à ò fi ìlú náà fún àwọn ará Kálídéà Ìwọ Olúwa Ọba sọ fún mi pé, Ra pápá náà pẹ̀lú owó fàdákà, kí o sì pe ẹlẹ́rìí   Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run gbogbo ẹran ara Ǹjẹ́ ohun kan há a ṣòro fún mi bí Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí Èmi ṣetan láti fi ìlú yìí fún àwọn ará Kálídéà àti fún Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ẹni tí yóò kó o Àwọn ará Kálídéà tí ó ń gbógun tí ìlú yóò wọ ìlú Wọn ó sì fi iná sí ìlú wọn ó jó o palẹ̀ ní ọ̀nà ilé tí àwọn ènìyàn ti ń mú mi bínú, tí wọ́n ń rúbọ tùràrí lórí pẹpẹ fún Báálì ti wọn sì ń da ẹbọ òróró fún Ọlọ́run mìíràn Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àti Júdà kò ṣe ohun kankan bí kò ṣe ibi lójúmi láti ìgbà èwe wọn Nítorí àwọn ọmọ Isreli ti fi kìkì iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n mú mi bínú ni Olúwa wí Láti ọjọ́ tí wọ́n ti kọ́ ọ, títí di àkókò yìí ni ìlú yìí ti jẹ́ ohun ìbínú àti ìyọnu fún mi tó bẹ́ẹ̀ tí èmi yóò fà á tu kúrò níwájú mi Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àti àwọn ènìyàn Júdà ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ìbàjẹ́ ni wọn tí wọ́n ṣe Àwọn Ísírẹ́lì, Ọba wọn àti gbogbo ìjòyè, àlùfáà àti wòlíì, àwọn ọkùnrin Júdà àti àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù Wọ́n kọ ẹ̀yìn sími, wọ́n sì yí ojú wọn padà Èmi kọ̀ wọ́n, síbẹ̀ wọn kò fetísílẹ̀ láti gbọ́ ẹ̀kọ́ tàbí kọbiara sí ìwà ìbàjẹ́ Wọ́n kó òrìṣà ìríra wọn jọ sí inú ilé tí wọ́n fi orúkọ mi pè, wọ́n sì sọ́ di àìmọ́ Wọ́n kọ́ ibi gíga fún Báálì ní àfonífojì Hínómù láti fi ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin rúbọ sí Mólékì Èmi kò páláṣẹ, fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò wá sí ọkàn mi pé kí wọ́n ṣe ohun ìríra wọ̀nyí tí ó sì mú Júdà ṣe Ìwọ ń sọ̀rọ̀ nípa ti ìlú yìí pé, Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn ni à ó fi wọ́n fún Ọba Bábílónì, ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nì yìí Èmi ó kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti lé wọn kúrò ní ìgbà ìbínú àti ìkáàánú ńlá mi Èmi yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀ yìí èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó máa gbé láìléwu Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn Èmi ó fún wọn ní ọkàn kan àti ìṣe kí wọn kí ó lè máa bẹ̀rù mi fún rere wọn àti fún rere àwọn ọmọ wọn tí ó tẹ̀lé wọn Èmi ò bá wọn dá májẹ̀mú ayérayé, èmi kò ní dúró láti ṣe rere fún wọn Èmi ó sì jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù mi, wọn kì yóò sì padà lẹ́yìn mi Èmi ó yọ̀ nípa ṣíṣe wọ́n ní rere, èmi ó sì fi dá wọn lójú nípa gbíngbìn wọ́n sí ilẹ̀ yìí tọkàntọkàn mi Nítorí bayìí ni Olúwa wí Gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú gbogbo ibi ńlá yìí wá sórí àwọn ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó mú gbogbo rere tí èmi ti sọ nípa ti wọn wá sórí wọn Lẹ́ẹ̀kan síi, pápá yóò di rírà ní ilẹ̀ yìí tí ìwọ ti sọ pé, Ohun òfò ni tí kò bá sí ọkùnrin tàbí àwọn ẹran, nítorí tí a ti fi fún àwọn ará Bábílónì Wọn ó fi owó fàdákà ra oko, wọn yóò fi ọwọ́ sí ìwé, wọn ó dí i pa pẹ̀lú ẹlẹ́rìí láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì àti ní ìlú kékèké tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká àti ní ìlú Júdà àti ní ìlú ọwọ́ òkè orílẹ̀ èdè ní ìhà gúṣù olókè ilẹ̀ àti ní Gúsù, nítorí èmi ó mú ìgbékùn wọn padà wá, ni Olúwa wí Ìlérí Ìmúpadàsípò Nígbà tí Jeremáyà wà nínú àgbàlá túbú, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ̀ ọ́ wá lẹ́ẹ̀kejì Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ẹni tí ó dá ayé, Olúwa tí ó mọ ayé tí ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, Olúwa ni orúkọ rẹ̀ Pè mí, èmi ó sì dá ọ lóhùn, èmi ó sì sọ ohun alágbára ńlá àti ọ̀pọ̀ ohun tí kò ṣe é wádìí tí ìwọ kò mọ̀ fún ọ Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì sọ nípa àwọn ilẹ̀ ìlú yìí àti ààfin àwọn Ọba Júdà tí ó ti wó lulẹ̀ nítorí àwọn ìdọ̀tí àti idà Nínú ìjà pẹ̀lú Kálídéà Wọn yóò kún fún ọ̀pọ̀ òkú ọmọkùnrin tí èmi yóò pa nínú ìbínú àti nínú ìrunú mi Èmi ó pa ojú mi mọ́ kúrò ní ìlú yìí nítorí gbogbo búburú wọn  Síbẹ̀, èmi ó mú okun àti ìwòsàn wá èmi ó wo àwọn ènìyàn mi sàn Èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó jẹ ìgbádùn ìyè lọ́pọ̀lọpọ̀ àti ìṣọ́ Èmi ó mú Júdà àti Ísírẹ́lì kúrò nínú ìgbékùn, èmi ó sì tún wọn kọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀ Èmi ó wẹ̀ wọ́n nù kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ sími Èmi ó sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àìṣedédé wọn sí mi jìn wọ́n Nígbà náà ni ìlú yìí ó fún mi ní òkìkí, ayọ̀, ìyìn àti ọlá níwájú gbogbo orílẹ̀ èdè ayé tí wọ́n gbọ́ gbogbo rere tí èmi ṣe fún wọn Wọn ó sì bẹ̀rù, wọn ó wárìrì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore àti àlàáfíà tí èmi pèṣè fún wọn Èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa ti ilẹ̀ yìí pé ó dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran Síbẹ̀ ní ìlú Júdà ní pópónà ti Jérúsálẹ́mù tí ó di àkọsílẹ̀ láìsí ẹni tó gbé ibẹ̀ yálà ní ọkùnrin tàbí àwọn ẹran, wọn ó gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí Ariwo di ayọ̀ àti inú dídùn, ohùn ìyàwó àti ti ọkọ ìyàwó àti ohùn àwọn tí ó ru ẹbọ ọpẹ́ wọn nílé Olúwa wí pé Yin Olúwa àwọn ọmọ ogun, nítorí Olúwa dára, ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé Nítorí èmi ó dá ìkólọ ilẹ̀ náà padà sí bí o ṣe wà tẹ́lẹ̀ ni Olúwa wí Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, Ní ilẹ̀ yìí tí ó ti dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran nínú gbogbo ìlú, kò ní sí pápá oko fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn láti mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sinmi Ní ìlú orílẹ̀ èdè òkè wọn, ní ìhà gúṣù ilẹ̀ olókè ní ilẹ̀ ti Bẹ́ńjámínì ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká àti ní ìlú Júdà ni agbo yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n, ni Olúwa wí  Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ṣẹ Ní ọjọ́ wọ̀n ọn nì àti ní àkókò náà, Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dáfídì Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà Ní ọjọ́ wọ̀n ọn nì, Júdà yóò di ẹni ìgbàlà Jérúsálẹ́mù yóò sì máa gbé láìséwu Orúkọ yìí ni a ó máa pè é Olúwa wa olódodo Nítorí báyìí ni Olúwa wí Dáfídì kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Ísírẹ́lì Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ ọmọ Léfì kò ní kùnà láti ní ọkùnrin kan tí ó dúró níwájú mi ní gbogbo ìgbà láti rú ẹbọ sísun ẹbọ jíjẹ àti láti pèsè ìrúbọ   Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremáyà wá wí pé Èyí ni ohun tí Olúwa sọ Tí ìwọ bá lè dá májẹ̀mú mi ní òru tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀sán àti òru kò lè sí ní àkókò wọn mọ́ Nígbà náà ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Léfì tí ó jẹ́ àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ níwájú mi lè bàjẹ́, tí Dáfídì kò sì rí ẹni láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ Èmi ó mú àwọn ọmọlẹ́yìn Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti Léfì tí ó jẹ́ oníwàásù níwájú mi di bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí kò ṣe é kà àti bí iyẹ̀pẹ̀ ojú òkun tí kò ṣe é wọ̀n   Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé Ǹjẹ́ ìwọ kò kíyèsí pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ pé Olúwa ti kọ àwọn Ọba méjèèjì tí ó yàn sílẹ̀ Nítorí náà, ni wọ́n ti ṣe kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi Wọn kò sì mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè kan Báyìí ni Olúwa wí Bí èmi kò bá ti da májẹ̀mú mi pẹ̀lú ọ̀sán àti òru àti pẹ̀lú òfin ọ̀run àti ayé tí kò lè yẹ̀ Nígbà náà ni èmi ó kọ ọmọlẹ́yìn Jákọ́bù àti Dáfídì ìránṣẹ́ mi tí èmi kò sì ní yan ọ̀kan nínú ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ alákóso lórí àwọn ọmọlẹ́yìn Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù nítorí èmi ó mú ìkólọ wọn padà èmi ó sì ṣàánú fún wọn   Ìbáwí Fún Sedekáyà Nígbà tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ Ọba tí ó jọba lé lórí ń bá Jérúsálẹ́mù jà, àti gbogbo àwọn ìlú tí ó yí ká, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa pé Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ọmọ ogun wí Lọ sí ọ̀dọ̀ Sedekáyà Ọba Júdà kí o sì sọ fún-un pé, Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí Èmi fẹ́ fa orílẹ̀ èdè yìí lé Ọba Bábílónì lọ́wọ́, yóò sì jó palẹ̀ Ìwọ kò ní sá àsálà, ṣùgbọ́n à ó mú ọ, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì fà ọ́ lé e lọ́wọ́ Ìwọ yóò rí Ọba Bábílónì pẹ̀lú ojú ara rẹ yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ lójúkojú ìwọ yóò sì lọ sí Bábílónì  Síbẹ̀, gbọ́ ìlérí Olúwa , ìwọ Sedekáyà Ọba Júdà Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí nípa rẹ ìwọ kì yóò ti ipa idà kú Ìwọ yóò kú ní àlàáfíà Bí àwọn ènìyàn sì ti ń ṣe iná ìsìnkú ní ọlá fún àwọn baba rẹ, Ọba tí ó jẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò ṣe iná ní ọlá rẹ, wọn ó sì pohùnréré pé, Yé, olúwa! Èmi fúnra mi ni ó ṣèlérí yìí ni Olúwa wí   Nígbà náà ni Jeremáyà wòlíì sọ gbogbo nǹkan yìí fún Sedekáyà Ọba Júdà ní Jérúsálẹ́mù Nígbà tí ogun Ọba Bábílónì ń bá Jérúsálẹ́mù jà, àti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù ní Júdà, Lákíṣì, Ásékà àwọn nìkan ni ìlú olódi tí ó kù ní Júdà Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremáyà wá lẹ́yìn ìgbà tí Ọba Sedekáyà ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù láti polongo ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú Kí oníkálùkù lè jẹ́ kí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin tí í ṣe Hébérù lọ lọ́fẹ̀ẹ́, kí ẹnikẹ́ni kí ó má mú ará Júdà arákùnrin rẹ̀ sìn Nítorí náà, gbogbo àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọwọ́ sí májẹ̀mú náà láti dá ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin sílẹ̀ kí wọ́n sì má ṣe fi wọ́n sínú ìgbékùn mọ́ Wọ́n sì gbà, wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ lọ́fẹ̀ẹ́ Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n yí ọkàn wọn padà wọ́n sì mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀ padà láti tún máa sìn wọ́n Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé Èyí ni ohun tí Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé Mo dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín nígbà tí mo mú wọn kúrò ní Éjíbítì kúrò ní oko ẹrú Mo wí pé, Ní ọdún keje, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ tú àwọn Hébérù tí wọ́n ti ta ara wọn fún un yín sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti sìn yín fún ọdún mẹ́fà Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn kí ó lọ ṣùgbọ́n àwọn baba yín kò gbọ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sími Láìpẹ́ yìí ẹ ti ronúpìwàdà, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì ṣe ìtúsílẹ̀ fún àwọn ènìyàn Ẹ sì tún bá mi dá májẹ̀mú ní àwọn ilé tí a ti ń pe orúkọ mi Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yípadà, ẹ sì sọ orúkọ mi di èérí, olúkúlùkù sì mú kí àwọn ẹni rẹ tí ó ti sọ di òmìnira bí ọkàn wọn ti fẹ́ padà ẹ̀yin sì tún fi wọ́n ṣe ẹrú Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí Ẹ̀yin kò fetí sími nípa ọ̀rọ̀ òmìnira láàrin ẹ̀gbọ́n sí àbúrò, láàrin ẹnìkan sí èkejì rẹ̀ Wò ó, èmi yóò kéde òmìnira fún un yín ni Olúwa wí Sí idà, sí àjàkálẹ̀-àrùn, àti sí ìyàn, èmi ó sì fi yín fún ìwọ̀sí ní gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé Èmi ó ṣe àwọn ọkùnrin náà tí ó da májẹ̀mú mi, tí kò tẹ̀lé májẹ̀mú tí wọ́n ti dá níwájú mi bí ẹgbọ̀rọ màlúù tí wọ́n gé sí méjì, tí ó sì kọjá láàrin ìpín méjì náà Àwọn ìjòyè Júdà àti àwọn ti Jérúsálẹ́mù, àwọn aláṣẹ àti àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó kọjá láàrin àwọn ìpín méjèèjì náà Èmi ó fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀ta wọn, àti lé àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́ Òkú wọn yóò jẹ́ oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko ìgbẹ́ Sédékáyà Ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní Júdà ni èmí yóò fi lé àwọn ọ̀ta wọn lọ́wọ́, àti àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn àti lé ọwọ́ ogun Bábílónì tí ó ti lọ kúrò lọ́dọ̀ yín Wò ó èmi ó pàṣẹ ni Olúwa wí, èmi ó sì mú wọn padà sí ìlú yìí, wọn ó sì baà jà, wọn ó sì kóo, wọn ó fi iná jóo Èmi ó sì sọ ìlú Júdà dí ahoro Àwọn Rékábù Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọjọ́ Jehóaikimu ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà wí pé Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rékábù, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sí ilé Olúwa , sí ọ̀kan nínú iyàrá wọ̀n-ọn-nì, kí o sì fún wọn ní ọtí wáìnì mu Nígbà náà ni mo mu Jmanáyà ọmọ Jeremáyà, ọmọ Hábásínáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ilé àwọn ọmọ Rékábù Mo sì mú wọn wá sí ilé Olúwa sínú iyàrá Hanani ọmọ Ígídálíà, ènìyàn Ọlọ́run, tí ó wà lẹ́bàá yàrá àwọn ìjòyè, tí ó wà ní òkè yàrá Mááséíà, ọmọ Sálúmù, olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà, Mo sì gbé ìkòkò tí ó kún fún ọtí wáìnì pẹ̀lú ago ka iwájú àwọn ọmọ Rékábù Mo sì wí fún wọn pé, Mu ọtí wáìnì Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, Àwa kì yóò mu ọtí wáìnì nítorí Jónádábù ọmọ Rékábù, baba wa pàṣẹ fún wa pé Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín láéláé Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tàbí kí ẹ fúnrúgbìn, tàbí kí ẹ gbin ọgbà àjàrà Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní ọ̀kankan nínú àwọn ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ní gbogbo ọjọ́ yín ni ẹ̀yin ó máa gbé inú àgọ́ kí ẹ̀yin kí ó lè wá ní ọjọ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ náà níbití ẹ̀yin ti ń ṣe àtìpó Báyìí ni àwa gba ohùn Jónádábù ọmọ Rékábù bàbá wa gbọ́ nínú gbogbo èyí tí ó palásẹ fún wa, kí a má mu ọtí wáìnì ní gbogbo ọjọ́ ayé wa àwa, àwọn aya wa, àwọn ọmọkùnrin wa, àti àwọn ọmọbìnrin wa Àti kí a má kọ́ ilé láti gbé bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ní ọgbà àjàrà tàbí oko, tàbí ohun ọ̀gbìn Ṣùgbọ́n àwa ń gbé inú àgọ́, a sì gbọ́ràn, a sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Jónádábù baba wa paláṣẹ fún wa Ó sì se, nígbà tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì gòkè wá sí ilẹ̀ náà àwa wí pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jérúsálẹ́mù, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Síríà Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jérúsálẹ́mù Nígbà yìí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, lọ, kí o sì sọ fún àwọn ọkùnrin Júdà, àti àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù pé, Ẹ̀yin kì yóò ha gba ẹ̀kọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ni Olúwa wí Ọ̀rọ̀ Jónádábù ọmọ Rékábù tí ó pa láṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì, ni a mú sẹ, wọn kò sì mu ọtí wáìnì títí di òní yìí, nítorí tí wọ́n gba òfin baba wọn Èmi sì ti ń sọ̀rọ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sími Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, Ẹ yípadà nísisiyìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sími Nítòótọ́, àwọn ọmọ Jónádábù ọmọ Rékábù pa òfin baba wọn mọ́ tí ó palásẹ fún wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò pa òfin mi mọ́ Nítorí náà, báyìí ni, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Júdà, àti sórí gbogbo olùgbé Jérúsálẹ́mù nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀ Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn   Nígbà náà ni Jeremáyà wí fún ìdílé Rékábù pé, Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé Nítorí tí ẹ̀yin gba òfin Jónádábù baba yín, tí ẹ sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó palásẹ fún un yín Nítorí náà, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, pé Jónádábù ọmọ Rékábù kì yóò fẹ́ ọkùnrin kan kù láti sìn mí   Jéhóíákímù Jó Ìwé Kíká Jeremáyà Ní ọdún kẹrin Jéhóíákímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé Mú ìwé kíká fún ará rẹ, kí o sì kọ sínú rẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ nípa Ísírẹ́lì àti ti Júdà, àti sí gbogbo orílẹ̀ èdè láti ìgbà tí mo ti sọ fún ọ láti ọjọ́ Jòsáyà títí di òní Ó lè jẹ́ wí pé ilé Júdà yóò gbọ́ gbogbo ibi tí mo ti pinnu láti ṣe fún wọn kí wọn kí ó sì yípadà, olúkúlùkù wọn kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀ Kí èmi kí ó lè dárí àìṣedédé àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n Nígbà náà ni Jeremáyà pe Bárúkì ọmọ Neráyà, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run báa sọ fún, Bárúkì sì kọ láti ẹnu Jeremáyà, gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ fún-un sórí ìwé kíká náà Nígbà náà ni Jeremáyà wí fún Bárúkì pé, A ṣé mi mọ́! Èmi kò lè lọ sí ilé Olúwa Nítorí náà, ìwọ lọ sí ilé Olúwa ní ọjọ́ ààwẹ̀, kí o sì kà nínú ìwé kíkà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ ti ẹnu mi kọ ìwọ ó sì kà á ní etí gbogbo Júdà, tí wọ́n jáde wá láti ìlú wọn Ó lè jẹ́ pé, ẹbọ wọn yóò wá sí iwájú Olúwa , wọ́n ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn nítorí pé títóbi ni ìbínú àti ìrunú tí Olúwa ti sọ sí àwọn ènìyàn yìí Bárúkì ọmọ Neráyà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí wòlíì Jeremáyà sọ fún, láti ka ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé ní ilé Olúwa Ní oṣù kẹ́sàn-án ọdún karùn-ún Jéhóíákímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà ni wọ́n kéde ààwẹ̀ níwájú Olúwa fún gbogbo ènìyàn Jérúsálẹ́mù àti fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wá láti Júdà Láti inú yàrá Gémáríà ọmọ Sáfánì akọ̀wé, ní àgbàlá òkè níbi ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa tuntun Bárúkì sì ka ọ̀rọ̀ Jeremáyà láti inú ìwé ní ilé Olúwa sí etí gbogbo ènìyàn Nígbà tí Míkáyà ọmọ Gémáríà ọmọ Sáfánì gbọ́ gbogbo àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé náà Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé Ọba sínú yàrá akọ̀wé níbi tí gbogbo àwọn ìjòyè gbé jókòó sí Élísámà akọ̀wé, Déláyà ọmọ Sámáyà, Elinátanì ọmọ Ákíbórì, Gémáríà ọmọ Sáfánì àti Sedekáyà ọmọ Hananáyà àti gbogbo àwọn ìjòyè Lẹ́yìn tí Míkáyà sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí o ti gbọ́ fún wọn, nígbà tí Bárúkì kà láti inú ìwé kíkà náà ní etí àwọn ènìyàn Gbogbo àwọn ìjòyè sì rán Jéhúdù ọmọ Métamáyà ọmọ Sélémáyà ọmọ Kúsì sí Bárúkì wí pé, mú ìwé kíká náà ní ọwọ́ rẹ láti inú èyí tí ìwọ kà ní etí àwọn ènìyàn kí o si wá Nígbà náà ni Bárúkì ọmọ Nétayà wá sí ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú ìwé kíká ní ọwọ́ rẹ̀ Wọ́n sì wí fún pé, Jòkòó, jọ̀wọ́ kà á sí etí wa! Nígbà náà ni Bárúkì sì kàá ní etí wọn Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà tan wọ́n ń wo ara wọn lójú pẹ̀lú ẹ̀rù Wọ́n sì wí fún Bárúkì pé, Àwa gbọdọ̀ jábọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Ọba Wọ́n sì bèèrè lọ́wọ́ Bárúkì pé, Sọ fún wa báwo ni o ṣe kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí Ṣé Jeremáyà ló sọ wọ́n Bárúkì sì dá wọn lóhùn wí pé, Bẹ́ẹ̀ ni, láti ẹnu rẹ̀ ni, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ báyìí fún mi, èmi sì fi tàdáwà kọ wọ́n sínú ìwé náà Nígbà náà ni àwọn ìjòyè sọ fún Bárúkì wí pé, Lọ fi ara rẹ pamọ́ àti Jeremáyà, má sì ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ibi tí ẹ̀yin wà Lẹ́yìn tí wọ́n fi ìwé kíkà náà pamọ́ sí iyàrá Elisámà akọ̀wé, wọ́n sì wọlé tọ Ọba lọ nínú àgbàlá, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà ní etí Ọba Ọba sì rán Jéhúdù láti lọ mú ìwé kíká náà wá láti inú iyàrá Elisámà akọ̀wé Ó sì ka ìwé náà ní etí Ọba àti ní etí gbogbo àwọn ìjòyè tí ó dúró ti Ọba Ó sì jẹ́ ìgbà òtútù nínú oṣù kẹsàn-án, Ọba sì jókòó ní ẹ̀bá iná àrò, iná náà sì ń jó ní iwájú rẹ̀ Nígbà tí Jéhúdù ka ojú ìwé mẹ́ta sí mẹ́rin nínú ìwé náà, Ọba fi ọ̀bẹ gé ìwé, ó sì sọ sínú iná tí ó wà nínú ìdáná, títí tí gbogbo ìwé náà fi jóná tán Síbẹ̀, Ọba àti gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò bẹ̀rù wọn kò sì fa aṣọ wọn yá Elinátanì, Déláyà àti Jemaríà sì bẹ Ọba kí ó má ṣe fi ìwé náà jóná, ṣùgbọ́n Ọba kọ̀ láti gbọ́ ti wọn Dípò èyí Ọba pàṣẹ fún Jeremélì ọmọ Hamelékì, Seráyà ọmọ Ásíráélì àti Selemáyà ọmọ Ábídélì láti mú Bárúkì akọ̀wé àti Jeremáyà wòlíì ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi wọ́n pamọ́ Lẹ́yìn tí Ọba fi ìwé kíkà náà tí ọ̀rọ̀ tí Bárúkì kọ láti ẹnu Jeremáyà jóná tán, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì tọ Jeremáyà wá Wí pé, tún mú ìwé kíká mìíràn kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé kíká èkínní tí Jéhóíákímù Ọba Júdà fi jóná Kí o sì wí fún Jéhóíákímù Ọba Júdà pé, Báyìí ni Olúwa wí Ìwọ ti fi ìwé kíká náà jóná, o sì wí pé, Èése tí ìwọ fi kọ̀wé sínú rẹ̀, pé lòótọ́ ni Ọba Bábílónì yóò wá, yóò sì pa ilẹ̀ run, àti ènìyàn, àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀ Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí níti Jéhóíákímù Ọba Júdà pé Òun kì yóò ní ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì, à ó sì sọ òkú rẹ̀ nù fún ooru ní ọ̀sán àti fún òtútù ní òru Èmi ó sì jẹ òun àti irú ọmọ rẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ̀ níyà nítorí àìṣedédé wọn èmi ó sì mú gbogbo ibi tí èmi ti sọ sí wọn wá sórí wọn, àti sórí àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn Júdà, nítorí tí wọn kò fetísí mi   Nígbà náà ni Jeremáyà mú ìwé kíká mìíràn fún Bárúkì akọ̀wé ọmọ Neráyà, ẹni tí ó kọ̀wé sínú rẹ̀ láti ẹnu Jeremáyà gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé tí Jéhóíákímù Ọba Júdà ti sun níná A sì fi onírúurú ọ̀rọ̀ bí irú èyí kún pẹ̀lú Jeremáyà Nínú Túbú Sedekáyà ọmọ Jòsáyà sì jọba nípò Kóráyà ọmọ Jéhóíákímù ẹni tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì fi jẹ Ọba ní ilẹ̀ Júdà Ṣùgbọ́n àti òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kò fetísí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípa wòlíì Jeremáyà Ṣedekáyà Ọba sì rán Jéhúkálì ọmọ Semeláyà àti Sefanáyà ọmọ Máséyà sí Jeremáyà wòlíì wí pé, Jọ̀wọ́ gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa Nígbà yìí Jeremáyà sì ń wọlé, ó sì ń jáde láàrin àwọn ènìyàn nítorí wọ́n ti fi sínú túbú Àwọn ọmọ ogun Fáráò ti jáde kúrò nílẹ̀ Éjíbítì àti nígbà tí àwọn ará Bábílónì tó ń ṣàtìpó ní Jérúsálẹ́mù gbọ́ ìròyìn nípa wọn, wọ́n kúrò ní Jérúsálẹ́mù Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run wá Èyí ni, ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì sọ fún Ọba àwọn Júdà tó rán ọ láti wádìí nípa mi Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáde láti kún ọ lọ́wọ́ yóò padà sílẹ̀ wọn sí Éjíbítì Nígbà náà ni àwọn ará Bábílónì yóò padà láti gbógun ti ìlú Wọn yóò mú wọn nígbèkùn, wọn yóò sì fi iná jó ìlú náà kanlẹ̀ Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí Ẹ má ṣe tan ara yín jẹ ní èrò wí pé, Àwọn ará Bábílónì yóò fi wá sílẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú wọn kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ Kódà tó bá ṣe pé wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí ń gbógun tì yín àti àwọn tí ìjàǹbá ṣe, tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ibùdó wọn wọn yóò jáde láti jó ìlú náà kanlẹ̀ Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì ti kúrò ní Jérúsálẹ́mù nítorí àwọn ọmọ ogun Fáráò Jeremáyà múra láti fi ìlú náà sílẹ̀, láti lọ sí olú ìlú Bẹ́ńjámínì láti gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ nínú ohun ìní láàrin àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀ Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ẹnu-bodè Bẹ́ńjámínì, olórí àwọn olùṣọ́ tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Íríjà ọmọ Ṣelemáyà ọmọ Hananáyà mú un, ó wí pé, Ìwọ ń yapa sí àwọn ará Bábílónì Jeremáyà sọ wí pé, Èyí kì í ṣe òtítọ́! Èmi kò yapa sí àwọn ará Bábílónì Ṣùgbọ́n Íríjà kọ tí ikún sí i, dípò èyí a mú Jeremáyà, ó sì mú un lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìjòyè Wọ́n bínú sí Jeremáyà, wọ́n jẹ ẹ́ níyà, wọ́n tún fi sí àtìmọ́lé nílé Jónátanì akọ̀wé nítorí wọ́n ti fi èyí ṣe ilé túbú Wọ́n fi Jeremáyà sínú túbú tí ó ṣókùnkùn biribiri níbi tí ó wà fún ìgbà pípẹ́ Nígbà náà ni Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ sí i, tí ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú wá sí ààfin níbi tí ó ti bi í ní ìkọ̀kọ̀ pé, Ìfẹ́ ọ̀rọ̀ kan wà láti ọ̀dọ̀ Olúwa Bẹ́ẹ̀ ni, Jeremáyà fèsì pé, wọn ó fi ọ́ lé ọwọ́ Ọba Bábílónì Nígbà náà, Jeremáyà sọ fún Ọba Sedekáyà pé, Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ yín, àwọn ìjòyè yín pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ẹ fi sọ mí sínú túbú Níbo ni àwọn wòlíì yín tí wọ́n ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ fún-un yín wí pé Ọba Bábílónì kò ní gbógun tì yín wá Ṣùgbọ́n ní báyìí, Olúwa mi Ọba jọ̀wọ́ gbọ́ Jẹ́ kí n mú ẹ̀dùn ọkàn mi tọ̀ ọ́ wá má ṣe rán mi padà sí ilé Jónátanì akọ̀wé, à fi kí n kú síbẹ̀ Ọba Sedekáyà wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi Jeremáyà sínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, àti kí wọn sì fún ní àkàrà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí àkàrà yóò fi tán bẹ́ẹ̀ ni Jeremáyà wà nínú àgbàlá náà Wọ́n Sọ Jeremáyà Sínú Àmù Sefatíà ọmọ Mátanì, Gédáyà ọmọ Páṣúrì, Jéhúdù ọmọ Selemáyà àti Páṣúrì ọmọ Málíkíà gbọ́ ohun tí Jeremáyà ń sọ fún àwọn ènìyàn nígbà tí ó sọ wí pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí Ẹnikẹ́ni tó bá dúró nínú ìlú yìí yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá lọ sí Bábílónì yóò yè yóò sá àsálà, yóò sì yè Àti pé èyí ni ohun tí Olúwa wí Ìdánilójú wà wí pé a ó fi ìlú náà lé ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí yóò sì kó wa nígbékùn   Nígbà náà ni àwọn ìjòyè wí fún Ọba pé, Ó yẹ kí a pa ọkùnrin yìí ó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ogun tó kù nínú ìlú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn nípa ohun tí ó ń sọ fún wọn Ọkùnrin yìí kò fẹ́ ire fún àwọn ènìyàn bí kò ṣe ìparun Sedekáyà Ọba sì wí pé, Ó wà lọ́wọ́ yín Ọba kò lè ṣe ohunkóhunm láti ta kò yín Wọ́n gbé Jeremáyà sọ sínú àmù Málíkíà ọmọ Ọbakùnrin tó wà ní àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, wọ́n ju Jeremáyà sínú àmù pẹ̀lú okùn kò sì sí omi níbẹ̀ àyàfi ẹrọ̀fọ̀ nìkan, Jeremáyà sì rì sínú ẹrọ̀fọ̀ Ṣùgbọ́n, Ebedimélékì, ará Kúṣì ìjòyè nínú ààfin Ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremáyà sínú àmù Nígbà tí Ọba jókòó lẹ́nubodè Bẹ́ńjámínì Ebedimélékì jáde kúrò láàfin ó sì sọ fún un pé, Olúwa mi Ọba, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ṣe ohun búburú sí Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run Wọ́n ti gbé e sọ sínú àmù níbi tí kò sí oúnjẹ kankan nínú ìlú mọ́ Nígbà náà ni Ọba pàṣẹ fún Ebedimélékì ará Kúṣì pé, Mú ọgbọ̀n ọkùnrin láti ibí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì lọ yọ Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run kúrò nínú àmù kí ó tó kú Ebedimélékì kó àwọn ọkùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n lọ sínú yàrá kan nínú ààfin Ọba Ó mú àwọn aṣọ àkísà àti okùn tọ Jeremáyà lọ nínú àmù Ebedimélékì sọ fún Jeremáyà pé, Fi àkísà àti okùn bọ abẹ́ abíyá rẹ, Jeremáyà sì ṣe bẹ́ẹ̀ Báyìí ni wọ́n ṣe yọ ọ́ jáde, ó sì ń gbé àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́ Nígbà náà ni Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ pe, Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti láti mú un wá sí ẹnubodè kẹta nílé Ọlọ́run Ọba sì sọ fún Jeremáyà pé, Èmi yóò bi ọ́ ní ohun kan má sì ṣe fi ohun kan pamọ́ fún mi Jeremáyà sì sọ fún Sedekáyà pé, Tí mo bá fún ọ ní èsì, ṣé o kò ní pa mí Tí mo bá gbà ọ́ nímọ̀ràn, o kò ní gbọ́ tèmi Ṣùgbọ́n Ọba Sedekáyà búra ní ìkọ̀kọ̀ fún Jeremáyà wí pé, Dájúdájú bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó fún wa ní ẹ̀mí, èmi kò ní pa ọ́ tàbí fà ọ́ fún àwọn tó ń lépa ẹ̀mí rẹ Nígbà náà ni Jeremáyà sọ fún Sedekáyà pé, Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Àyàfi bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn olóyè Ọba Bábílónì, a ó dá ẹ̀mí rẹ sí àti pé ìlú yìí kò ní di jíjó níná ìwọ àti ilé rẹ yóò sì wà láàyè Ṣùgbọ́n tí o kò bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ìjòyè Ọba Bábílónì, a ó fa ìlú yìí lé ọwọ́ àwọn Bábílónì Wọn yóò sì fi ina sun-un, ìwọ gan-an kò ní le sá mọ́ wọn lọ́wọ́   Ọba Sedekáyà sọ fún Jeremáyà pé, Mò ń bẹ̀rù àwọn Júù tó ti sálọ sí ilẹ̀ Bábílónì, nítorí pé àwọn ará Bábílónì lè fà mí lé wọn lọ́wọ́ láti fìyà jẹ mí Jeremáyà sì dáhùn wí pé, Wọn kò ní fi ọ́ lé e lọ́wọ́ Pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ nípa ṣíṣe ohun tí mo sọ fún ọ yóò sì dára fún ọ, ẹ̀mí rẹ yóò sì wà Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ, èyí ni ohun tí Olúwa ti fi hàn mí Gbogbo àwọn obìnrin tó kù ní ààfin Ọba Júdà ni wọn yóò kó jáde fún àwọn ìjòyè Ọba Bábílónì Àwọn obìnrin náà yóò sì sọ fún ọ pé  Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì borí rẹ Ẹsẹ̀ rẹ rì sínú orọ̀fọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti fi ọ́ sílẹ̀ Wọn yóò kó àwọn ìyàwó àti ọmọ rẹ wá sí Bábílónì Ìwọ gan-an kò ní bọ́ níbẹ̀, Ọba Bábílónì yóò mú ọ, wọn yóò sì jó ìlú yìí kanlẹ̀ Nígbà náà ni Sedekáyà sọ fún Jeremáyà pé, Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, tàbí kí o kú Tí àwọn ìjòyè bá mọ̀ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n bá wá bá ọ wí pé, Sọ fún wa ohun tí o bá Ọba sọ tàbí ohun tí Ọba sọ fún ọ má ṣe fi pamọ́ fún wa tàbí kí a pa ọ́, nígbà náà kí o sọ fún wọn, Mò ń bẹ Ọba láti má jẹ́ kí n padà lọ sí ilé Jónátanì láti lọ kú síbẹ̀   Gbogbo àwọn olóyè sì wá sí ọ̀dọ̀ Jeremáyà láti bi í léèrè, ó sì sọ gbogbo ohun tí Ọba ní kí ó sọ Wọn kò sì sọ ohunkóhun mọ́, nítorí kò sí ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí òun àti Ọba jọ sọ Jeremáyà wà nínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́ títí di ọjọ́ tí wọ́n fi kó Jérúsálẹ́mù Ìṣubú Jérúsálẹ́mù Bí wọ́n ṣe kó Jérúsálẹ́mù nìyìí Ní ọdún kẹsàn-án Sedekáyà Ọba Júdà, nínú oṣù kẹwàá Nebukadinésárì Ọba gbógun ti Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sì gẹ̀gùn tì í Ní ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù kẹrin ọdún kọkànlá Nebukadinésárì wọ́n ya wọ odi ìlú Nígbà náà ni gbogbo àwọn ìjòyè Ọba Bábílónì wá, wọ́n sì jókòó ní àárin ẹnubodè Nágálì Sárésérì Nígbà tí Sedekáyà Ọba Júdà àti àwọn ọmọ ogun rí wọn, wọ́n sá, wọ́n kúrò ní ìlú ní alẹ́, wọ́n gba ọ̀nà ọgbà Ọba lọ láàrin ẹnubodè pẹ̀lú odi méjì, wọ́n dojúkọ aginjù Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì lé wọn, wọ́n bá Sedekáyà láàrin ihà Jẹ́ríkò Wọ́n mú un ní ìgbékùn, wọ́n sì mú u tọ Nebukadinésárì Ọba Bábílónì àti Rábílà ní ilẹ̀ Hámátì, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀ Níbẹ̀ ní Rábílà, ni Ọba Bábílónì ti dúńbú àwọn ọmọ Sedekáyà lójú rẹ̀, tí ó sì tún pa gbogbo àwọn ọlọ́lá ilẹ̀ Júdà Nígbà náà ni ó fọ́ ojú Sedekáyà, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti gbé e lọ sí ilẹ̀ Bábílónì Àwọn Bábílónì dáná sun ààfin Ọba àti ilé àwọn ènìyàn, wọ́n sì wó odi Jérúsálẹ́mù Nebukadinésárì olórí àwọn ọmọ ogun mú lọ sí ìgbékùn Bábílónì pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú ìlú Ṣùgbọ́n Nebukadinésárì olórí ogun fi àwọn aláìní sílẹ̀ ní Júdà, àwọn tí kò ní ohun kankan ní àkókò náà, ó fún wọn ní ọgbà àjàrà àti oko Nísinsìnyìí, Nebukadinésárì Ọba àwọn Bábílónì pàṣẹ lórí Jeremáyà, láti ọ̀dọ̀ Nebusárádánì olórí ogun wá wí pé Ẹ gbé e, kí ẹ sì bojú tó o Ẹ má ṣe ṣe ohun búburú fún un, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá béèrè ni kí ẹ fi fún un Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú, Nebusárádánì olùdarí ọmọ ogun, Nebusasibánì, olóyè àgbà, Nágálì Sárésà, olóyè àgbà àti gbogbo àwọn olóyè ọba, ránṣẹ́ láti mú Jeremáyà kúrò nínú túbú Wọ́n gbé e lọ fún Jedalíyà ọmọ Álúkámù ọmọ Sápámù láti mú padà lọ sí ilé àti máa wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ Nígbà tí Jeremáyà wà nínú túbú, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ọ́ wá wí pé Lọ sọ fún Ebedimélékì ará Kúṣì, Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Èmi ṣetan láti mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ lórí ìlú yìí nípa àjálù kì í ṣe àlàáfíà Ní àkókò náà ni yóò ṣẹ lójú rẹ Ṣùgbọ́n Èmi yóò gbà ọ́ lọ́jọ́ náà ni Olúwa wí A kò ní fi ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí o bẹ̀rù Èmi yóò gbà ọ́ là o kò ní ṣubú láti ipa idà ṣùgbọ́n ìwọ yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ, nítorí pé ìwọ ní ìgbàgbọ́ nínú mi, ni Olúwa wí   Àjàkálẹ̀ Ààrùn Láti Ilẹ̀ Gúṣù Tí ìwọ yóò bá padà, Ìwọ Ísírẹ́lì padà tọ̀ mí wá, ni Olúwa wí Tí ìwọ yóò bá sì mú àwọn òrìṣà tí ìwọ ń ṣe kúrò níwájú mi, tí o kò sì yapa, Tí ó bá jẹ́ lóòtọ́ àti òdodo ni ìwọ búra Nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láàyè, nígbà náà ni orílẹ̀ èdè yóò di alábùkún fún nípaṣẹ̀ rẹ àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn Júdà àti Jérúsálẹ́mù Hú gbogbo ilẹ̀ tí ẹ kò lò rí, kí o má sì ṣe gbìn sáàrín ẹ̀gún Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwa kọ ọkàn rẹ ní ilà ẹ̀yin ènìyàn Júdà àti gbogbo ènìyàn Jérúsálẹ́mù, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná, nítorí ibi tí o ti ṣe kì yóò sí ẹni tí yóò pa á Kéde ní Júdà, kí o sì polongo ní Jérúsálẹ́mù, kí o sì wí pé fun fèrè káàkiri gbogbo ilẹ̀ Kí o sì kígbe, kó ara jọ pọ̀! Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi Fi àmì láti sálọ sí Síónì hàn, sálọ fún ààbò láìsí ìdádúró Nítorí èmi ó mú àjálù láti àríwá wá, àní ìparun tí ó burú jọjọ Kìnnìún ti sá jáde láti inú ibùgbé rẹ̀, apanirun orílẹ̀ èdè sì ti jáde Ó ti fi àyè rẹ̀ sílẹ̀ láti ba ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́ Ìlú rẹ yóò di ahoro láìsí olùgbé Nítorí náà, gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀ káàánú, kí o sì pohùnréré ẹkún, nítorí ìbínú ńlá Olúwa kò tí ì kúrò lórí wa Ní ọjọ́ náà, ni Olúwa wí pé, àwọn Ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn, àwọn àlùfáà yóò wárìrì, àwọn wòlíì yóò sì fòyà Nígbà náà ni mo sì wí pé, Áà! Olúwa àwọn ọmọ-ogun, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jérúsálẹ́mù jẹ nípa sísọ wí pé, Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà, nígbà tí o fẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa Nígbà náà ni a ó sọ fún Jérúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn pé, Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́ Ẹ̀fúùfù líle tí ó wá láti ọ̀dọ̀ mi Báyìí mo kéde ìdájọ́ mi lórí wọn Wò ó! O ń bò bí ìkuukùu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líle Ẹ̀ṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọ Ègbé ni fún wa àwa parun Ìwọ Jérúsálẹ́mù, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yè Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ Ohùn kan sì ń kéde ní Dánì Ó ń kókìkí ìparun láti orí òkè Éfúráímù wá Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀ èdè, kéde rẹ̀ fún Jérúsálẹ́mù pé Ọmọ ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jínjìn wá Wọ́n sì ń kígbe ogun láti dojú kọ ìlú Júdà Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá, nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,  ni Olúwa wí Ìwà rẹ àti ìṣe rẹ ló fa èyí bá ọ Ìjìyà rẹ sì nìyìí, Báwo ló ti ṣe korò tó! Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí! Áà! Ìrora mi, ìrora mi! Mo yí nínú ìrora Áà!, ìrora ọkàn mi! Ọkàn mi lù kìkì nínú mi, N kò le è dákẹ́ Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè, Mo sì ti gbọ́ igbe ogun Ìparun ń gorí ìparun Gbogbo ilẹ̀ náà sì ṣubú sínú ìparun Lọ́gán a wó àwọn àgọ́ mi, tí ó jẹ́ ohun ààbò mi níṣẹ́jú kan Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí ogun tí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè Aṣiwèrè ni àwọn ènìyàn mi wọn kò mọ̀ mí Wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n ọmọ wọ́n sì jẹ́ aláìlóye Wọ́n mọ ibi ṣíṣe wọn kò mọ bí a ti í ṣe rere Mo bojú wo ayé, ó sì wà ní júujùu, ó sì ṣófo àti ní ọ̀run, ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì sí Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n wárìrì gbogbo òkè kékèké mì jẹ̀jẹ̀ Mo wò yíká n kò rí ẹnìkan gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ló ti fò lọ Mo bojú wò, ilẹ̀ eléṣo, ó sì di aṣálẹ̀ gbogbo àwọn ìlú inú rẹ̀ sì ṣubú sínú ìparun níwájú Olúwa àti níwájú ríru ìbínú rẹ̀ Èyí ni ohun tí Olúwa wí Gbogbo ìlú náà yóò sì di ahoro, síbẹ̀ èmi kì yóò pa á run pátapáta Nítorí náà, ayé yóò pohùnréré ẹkún àwọn ọ̀run lókè yóò ṣóòkùn nítorí mo ti sọ, mo sì ti pète rẹ̀ mo ti pinnu, n kì yóò sì yí i padà Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafà gbogbo ìlú yóò sálọ Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ Gbogbo ìlú náà sì di ahoro kò sì sí ẹnìkan nínú rẹ̀ Kí ni ò ń ṣe, ìwọ tí o ti di ìjẹ tán Ìwọ ìbá wọ ara rẹ ní aṣọ òdodo kí o sì fi wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́ Àwọn olólùfẹ́ rẹ kẹ́gàn rẹ wọ́n sì ń lépa ẹ̀mí rẹ Mo gbọ́ ìró kan bí i igbe obìnrin tó ń rọbí, tí ó ń rọbí, ìrora bí i abiyamọ ọmọbìnrin Síónì tí ń pohùnréré ẹkún ara rẹ̀ Tí ó na ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì wí pé, Kíyèsí i mo gbé, Nítorí a ti fi ẹ̀mí mi lé àwọn apani lọ́wọ́ A Tú Jérúsálẹ́mù Sílẹ̀ Ọ̀rọ̀ náà sì tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa lẹ́yìn tí Nebukadinésárì balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti tú u sílẹ̀ ní Rámà Ó rí Jeremáyà tí a fi ẹ̀wọ̀n dè láàrin gbogbo àwọn tí wọ́n mú ní Jérúsálẹ́mù àti Júdà Wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì Bábílónì Nígbà tí balógun ẹ̀ṣọ́ rí Jeremáyà, ó sọ fún-un wí pé, Olúwa Ọlọ́run rẹ ni ó pàṣẹ ibí yìí fún mi Nísinsìn yìí, Olúwa ti mú un jáde ó ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò ṣe Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wí pé ẹ̀yin ènìyàn ṣẹ̀ sí Olúwa , àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀ Ṣùgbọ́n, ní òní yìí mò ń tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọwọ́ rẹ Bí o bá fẹ́, tẹ̀lémi kálọ sí Bábílónì, èmi yóò sì bojútó ọ ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá fẹ́, má ṣe wá Wò ó, gbogbo orílẹ̀ èdè wà níwájú rẹ, lọ sí ibikíbi tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn Ẹ̀wẹ̀, kí ó tó di pé Jeremáyà pẹ̀yìn dà láti máa lọ, Nebusárádánì fikún un wí pé, Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Jedaláyà ọmọ Álíkámù, ọmọ Sáfánì, ẹni tí Ọba Bábílónì ti yàn gẹ́gẹ́ bí olórí lórí ìlú Júdà, kí o sì máa gbé ní àárin àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o máa lọ ibikíbi tí ó bá wù ọ́ Nígbà náà ni balógun náà fún un ní oúnjẹ àti ẹ̀bùn, ó sì jẹ́ kí ó lọ Báyìí ni Jeremáyà lọ sí ọ̀dọ̀ Jedáláyà ọmọkùnrin Áhíkámù ní Mísípà, ó sì dúró tì í láàrin àwọn ènìyàn tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ náà Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn tí wọ́n kù lórí orílẹ̀ èdè náà gbọ́ pé Ọba Bábílónì ti yan Jedáláyà ọmọkùnrin Áhíkámù gẹ́gẹ́ bí gómìnà ní ilẹ̀ náà àti pé ó ti fi àwọn ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé tí wọ́n jẹ́ talákà ní ilẹ̀ náà tí wọn kò kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì sí ìkáwọ́ rẹ̀ Wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jedáláyà ní Mísípà, Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà, Jóhánónì àti Jónátanì ọmọkùnrin ti Káréà, Séráyà ọmọkùnrin Tánúmétì tí í ṣe ọmọkùnrin Épáì ti Nétópátè àti Jásáníà ọmọkùnrin Mákétè àti àwọn ènìyàn wọn Jedáláyà ọmọkùnrin Áhíkámù, ọmọkùnrin ti Sáfánì ṣe ìbúra láti tún fi dá àwọn ènìyàn lójú pé, Ẹ má ṣe bẹ̀rù láti sin àwọn Bábílónì Ó sọ wí pé, Gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa sin Ọba Bábílónì, yóò sì dára fún un yín Èmi fúnra mi yóò dúró ní Mísípà láti ṣojú yín níwájú Bábílónì tí wọ́n tọ̀ wá wá Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni yóò máa kórè ọtí wáìnì, èso igi àti òróró kí ẹ sì kó wọn sí inú àpò àpamọ́ yín kí ẹ̀yin sì máa gbé ní ilẹ̀ tí ẹ ti gbà Nígbà tí gbogbo àwọn Júdà ní Móábù, Ámónì, Édómù àti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè gbọ́ pé Ọba Bábílónì ti fi ohun tó kù sílẹ̀ ní Júdà, àti pé ó ti yan Jedáláyà ọmọkùnrin Áhíkámù ọmọkùnrin Sáfánì gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí wọn Gbogbo wọn padà wá sí ilẹ̀ Júdà sọ́dọ̀ Jedáláyà ní Mísípà láti orílẹ̀ èdè gbogbo tí a ti lé wọn sí Wọ́n sì kórè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí wáìnì àti èṣo igi Jóhánánì ọmọkùnrin ti Káréà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó kù ní orílẹ̀ èdè sì tọ Jedáláyà wá ní Mísípà Wọ́n sì sọ fún un wí pé, Ǹjẹ́ ìwọ ha mọ̀ pé Báálísì Ọba àwọn Ámónì ti rán Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà láti lọ mú ẹ̀mí rẹ Ṣùgbọ́n Jedáláyà ọmọkùnrin ti Áhíkámù kò gbà wọ́n gbọ́ Nígbà náà ni Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà sọ ní ìkọ̀kọ̀ fún Jedáláyà ní Mísípà pé, Jẹ́ kí èmi lọ pa Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ èyí Kí ni ìdí rẹ̀ tí yóò ṣe mú ẹ̀mí rẹ, tí o sì ṣe fẹ́ mú àwọn Júù tí ó yí ọ ká túká, kí ìyókù Júdà sì parun Ṣùgbọ́n Jedáláyà ọmọ Áhíkámù sọ fún Jóhánánì ọmọ Káréà pé, Má ṣe ṣe nǹkan yìí! Nítorí nǹkan tí ò ń sọ nípa Íṣímáẹ́lì kì í ṣe òtítọ́ Sísa Lọ Sí Éjíbítì Ní oṣù keje Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà, ọmọkùnrin Élísámà ti ìdílé Ọba, tí ó sì ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè Ọba, tọ Jedaláyà ọmọ Áhíkámù ti Mísípà wá pẹ̀lú ọkùnrin mẹ́wàá Nígbà tí wọ́n ń jẹun papọ̀ Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Jedaláyà ọmọ Áhíkámù, ọmọ Sáfánì pẹ̀lú idà Wọ́n sì pa á, ẹni tí Ọba Bábílónì ti yàn gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí ilẹ̀ náà Íṣímáẹ́lì sì tún pa gbogbo àwọn Júù tí wọ́n wà pẹ̀lú Jedaláyà ní Mísípà, àti gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí wọ́n wà níbẹ̀ bákan náà Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n pa Jedaláyà kí ó tó di wí pé ẹnikẹ́ni mọ̀ Àwọn ọgọ́rin ọkùnrin wá láti Ṣékémù, Ṣílò àti Saaríà, wọ́n fa irùngbọ̀n wọn, wọ́n ya aṣọ wọn, wọ́n sá ara wọn lọ́gbẹ́ wọ́n mú ẹbọ ọpẹ́ àti tùràrí wá sí ilé Olúwa Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà jáde kúrò láti Mísípà láti lọ pàdé wọn Ó sì ń sunkún bí ó ti ṣe ń lọ, nígbà tí ó pàdé wọn, ó wí pé, Ẹwá sọ́dọ̀ Jedaláyà ọmọkùnrin Álíkámù Nígbà tí wọ́n dé ìlú náà Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nètanáyà àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì sọ òkú wọn sínú ìhò kan Ṣùgbọ́n mẹ́wàá nínú wọn sọ fún Ísímáẹ́lì pé, Má se pa wá! Àwa ní ọkà àti Bálì, òróró àti oyin ní ìpamọ́ nínú oko Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀ kò sì pa wọ́n pẹ̀lú àwọn yóòkù Nísinsìn yìí, ihò náà tí ó kó gbogbo ara àwọn ọkùnrin tí ó ti pa pẹ̀lú Jedaláyà sí ni Ọba Aṣa ń lò gẹ́gẹ́ bí i ààbò nítorí Ọba Báṣì ti Ísírẹ́lì Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà sì ti kó òkú kún inú rẹ̀ Ísímáẹ́lì sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní Mísípà nígbèkùn, ọmọbìnrin Ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tó kù síbẹ̀ lórí àwọn tí Nebusarádánì balógun àwọn ẹ̀sọ́ ti fi yan Gédáláyà ọmọkùnrin Álíkámù ṣe olórí Isímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà kó wọn ní ìgbèkùn, ó sì jáde rékọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn Ámónì Nígbà tí Johánánì ọmọkùnrin Kárè àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ nípa gbogbo ìpànìyàn náà tí Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà ti ṣe Wọ́n kó gbogbo àwọn ọkùnrin wọn, wọ́n sì, lọ bá Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà jà Wọ́n pàdé rẹ̀ ní odò kan lẹ́bàá Gídéónì Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn Ísímáẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ rí Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì yọ̀ Gbogbo àwọn ènìyàn tí Ísímáẹ́lì ti kó ní ìgbékùn ní Mísípà yípadà, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ Jóhánánì ọmọ Káréà Ṣùgbọ́n Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà àti àwọn mẹ́jọ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ Jóhánánì, wọ́n sì sálọ sí Ámónì Lẹ́yìn náà Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tí wọn wà pẹ̀lú rẹ̀ sì kó gbogbo àwọn tí ó kù ní Mísípà àwọn tí ó ti rí gbà lọ́wọ́ Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa Gédáláyà ọmọ Álíkámù Àwọn ọmọ ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn olórí ilé ẹjọ́ tí ó ti kó wa láti Gíbíónì Wọ́n sì dúró ní Gérútì Kímámù ní ẹ̀bá Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nínú ìrìnàjò wọn sí Éjíbítì Láti gba àwọn Bábílónì sílẹ̀ Wọ́n bẹ̀rù wọn nítorí wí pé, Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà ti pa Jedaláyà ọmọ Álíkámù èyí tí Ọba Bábílónì ti yàn gẹ́gẹ́ bí i gómínà lórí ilẹ̀ náà Nígbà náà ní gbogbo àwọn ọmọ ogun àti Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti Jésánáyà omọkùnrin Hòsáyà àti kékeré títí dé orí ẹni ńlá wá Sí ọ̀dọ̀ Jeremáyà wòlíì náà, wọ́n sì sọ fún un pé, Jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún gbogbo ìyókù yìí Nítorí gẹ́gẹ́ bi ìwọ ṣe rí i nísinsin yìí pé a pọ̀ níye nígbà kan rí ṣùgbọ́n báyìí àwa díẹ̀ la sẹ́kù Gbàdúrà pé kí Olúwa Ọlọ́run rẹ sọ ibi tí àwa yóò lọ fún wa àti ohun tí àwa yóò ṣe Wòlíì Jeremáyà sì dáhùn wí pé, Mo ti gbọ́ Èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ṣe bèèrè Èmi yóò sọ gbogbo ohun tí Olúwa bá sọ fún un yín, ń kò sì ní fi ohunkóhun pamọ́ fún un yín Nígbà náà ni wọ́n sọ fún Jeremáyà wí pé, Kí Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ àti òdodo láàrin wa, bí àwa kò bá ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá rán ọ láti sọ fún wa Ìbá à ṣe rere, ìbá à ṣe búburú, àwa yóò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run wa èyí tí àwa ń rán ọ sí Kí ó ba à lè dára fún wa Nítorí pé àwa yóò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run wa Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé Nígbà náà ni a ó pa Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ àti gbogbo àwọn ènìyàn láti orí ẹní tí ó kéré dé orí ẹni ńlá Ó sì wí fún wọn pé, Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì wí Èyí ni ẹni tí ẹ̀yin ti rán láti gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ ṣíwájú mi Bí ẹ̀yin bá gbé ní ilẹ̀ yìí, èmi yóò gbé e yín ró, n kò sí ní fà yín lulẹ̀, èmi yóò gbìn yín, n kì yóò fà yín tu nítorí wí pé èmi yí ọkan padà ní ti ibi tí mo ti ṣe sí i yín Ẹ má ṣe bẹ̀rù Ọba Bábílónì tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù, báyìí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ ni Olúwa wí nítorí tí èmi wà pẹ̀lú yín láti pa yín mọ́ àti láti gbàyín ní ọwọ́ rẹ̀ Èmi yóò fi àánú hàn sí i yín, kí ó lè ṣàánú fún un yín, kí ó sì mú un yín padà sí ilẹ̀ yín Àmọ́ ṣá, bí ẹ̀yin bá wí pé, Àwa kò ní gbé ilẹ̀ yìí, ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín Àti pé bí ẹ̀yin bá wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò lọ gbé ní Éjíbítì níbi tí àwa kì yóò rí ìró ogunkógun, tí a kì yóò sì gbọ́ ìró fèrè, tí ebi oúnjẹ kì yóò sì pa wá, níbẹ̀ ni àwa ó sì máa gbé, Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ìyókù Júdà èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí Bí ẹ̀yin bá pinnu láti lọ sí Éjíbítì láti lọ ṣe àtìpó ńibẹ̀ Yóò sì ṣe, idà tí ẹ̀yin bẹ̀rù yóò sì lé e yín bá níbẹ̀ àti ìyànu náà tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù yóò sì tẹ̀lé yín lọ sí Éjíbítì àti pé ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò kú sí Nítorí náà, gbogbo àwọn tí ó ti pinnu láti ṣe àtìpó ní Éjíbítì ni yóò ti ipa idà kú, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn kò sì ní jẹ́ kí ẹníkẹ́ni nínú wọn yè tàbí sá àsálà nínú ibi tí èmi yóò mú wá sórí wọn Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Gẹ́gẹ́ bí èmi ti da ìbínú àti ìrunú síta sórí àwọn tí ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ ni ìrunú mi yóò dà sita sórí yín, nígbà tí ẹ̀yin bá lọ sí Éjíbítì Ẹ̀yin ó sì di ẹni ègún àti ẹní ẹ̀gàn àti ẹ̀sín, ẹ̀yin kì yóò sì rí ibí yìí mọ́ Ẹ̀yin yóòkù Júdà, Olúwa ti sọ fún un yín pé, Kí ẹ má ṣe lọ sí Éjíbítì Ẹ mọ èyí dájú Èmi kìlọ̀ fún un yín lónìí Pé àṣìṣe ńlá gbáà ni ẹ̀yin ṣe nígbà tí ẹ̀yin rán mi sí Olúwa Ọlọ́run yín pé, Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa sọ fún wa gbogbo ohun tí ó bá sọ, àwa yóò sì ṣe é Mo ti sọ fún un yín lónìí, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹ̀yin kò tí ì gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run yín, àti gbogbo ohun tí ó rán mi láti sọ fún un yín Ǹjẹ́ nísinsìnyìí ẹ mọ èyí dájú pé Ẹ̀yin yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn níbikíbi tí ẹ̀yin bá fẹ́ lọ láti ṣe àtìpó Nígbà tí Jeremáyà párí sísọ ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rán an sí wọn tan Ásáríyà ọmọ Hòsáyà àti Jóhánánì ọmọ Káréà, àti gbogbo àwọn agbéraga ọkùnrin sọ fún Jeremáyà pé, Irọ́ ló ń pa! Olúwa Ọlọ́run wa kò rán ọ láti sọ pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí Éjíbítì láti tẹ̀dó síbẹ̀ Ṣùgbọ́n Bárúkù ọmọ Néríà ń kó sí ọ lọ́kàn sí wa láti fàwá lé Bábílónì lọ́wọ́, kí wọn le pa wá tàbí kó wa sí ìgbékùn Bábílónì Nítorí náà, Jóhánánì ti Káréà àti àwọn ọ̀gágun, àti gbogbo àwọn ènìyàn tàpá sí àṣẹ Olúwa nípa dídúró sí Júdà Dípò bẹ́ẹ̀, Jóhánánì ọmọ Káréà àti àwọn ọ̀gágun sì ko àwọn àjẹkù Júdà tí wọ́n wá láti gbé ilẹ̀ Júdà láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ti tú wọn ká Wọ́n tún kó àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àti àwọn ọmọ Ọba tí ó jẹ́ obìnrin èyí tí Nebusàrádánì tí ó jẹ́ adarí ogun ọ̀wọ́ tí ó jẹ́ olùsọ́ ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú Jedaháyà ọmọ Élíkámù, ọmọ Sáfánì, àti Jeremáyà wòlíì náà àti Bárúkù ọmọ Néríà Nítorí náà, wọn wọ Éjíbítì pẹ̀lú àìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa , wọ́n sì lọ títí dé Táfánésì Ní Táfánésì ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá Nígbà tí àwọn Júù ń wòye mú àwọn òkúta pẹ̀lú rẹ, kí o sì rì wọ́n mọ́ inú amọ̀ tí ó wà nínú bíríkì tí ó wà níbi pèpéle ẹnu ọ̀nà ààfin Fáráò ní Táfánésì Báyìí kí o sì sọ fún wọn pé, Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Èmi yóò ránsẹ́ sí ìránṣẹ́ mi Nebukadinésárì Ọba Bábílónì Èmi yóò gbé ìjọba rẹ̀ ka orí àwọn òkúta èyí tí mo ti rì sí ibí yìí, yóò tan ìjọba rẹ̀ jù wọ́n lọ Yóò gbé ogun sí Éjíbítì yóò mú ikú bá àwọn tí ó yan ikú ìgbèkùn fún àwọn tí ó ti yan ìgbèkùn, àti idà fún àwọn tí ó yan idà Yóò dá, iná sun Tẹ́ḿpìlì àwọn òrìṣà Éjíbítì, yóò sun Tẹ́ḿpìlì àwọn òrìṣà Éjíbítì, yóò sì mú wọn lọ ìgbèkùn Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn, yóò ró aṣọ rẹ̀ mọ́ra, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò ró Éjíbítì òun yóò sì lọ kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà Ní Tẹ́ḿpìlì ni yóò ti fọ́ ère ilé òòrùn tí ó wà ní ilẹ̀ Ìjíbítì túútúú, yóò sì sun àwọn Tẹ́ḿpìlì àwọn òrìṣà Éjíbítì   Àjálù Nítorí Sinsin Òrìṣà Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Éjíbítì ní Mígídò, Táfánásì àti Mémífísì àti ní apá òkè Íjíbìtì Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Wo ibi tí mo mú bá Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ìlú Júdà Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀ Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, Má ṣe àwọn ohun búburú tí èmi kò fẹ́ Ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ láti fi ọkàn si Wọn kò sì yípadà kúrò nínú búburú wọn tàbí dáwọ́ ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà dúró Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Júdà àti òpópó Jérúsálẹ́mù àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí Kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Júdà ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lu ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Éjíbítì, níbi tí ẹ wá láti máa gbé Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè ayé gbogbo Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn bàbá ńlá yín àti àwọn Ọba àwọn ayaba Júdà, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Júdà àti ní òpópó Jérúsálẹ́mù Láti ìgbà náà sí àkókò yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ tàbí fi ìtẹ́ríba hàn tàbí kí wọn ó tẹ̀lé òfin àti àṣẹ tí mo pa fún un yín àti àwọn baba yín Fún ìdí èyí, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì wí Mo ti pinnu láti mú ibi wá sí orí yín àti láti pa Júdà run Èmi yóò sì mú àwọn èérún tí ó kù ní Júdà, tí wọ́n ṣetán láti lọ Éjíbítì Wọn yóò ṣubú pẹ̀lú idà tàbí kí wọn kú pẹ̀lú ìyàn láti orí ọmọdé títí dé àgbà ni wọn yóò kú láti ọwọ́ ìyàn tàbí idà Wọn yóò di ẹni ìfiré àti ìparun, ẹni ẹ̀kọ̀ àti ẹni ẹ̀gàn Èmi yóò fi ìyà jẹ ẹni tí ó bá ń gbé ní Éjíbítì pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn bí mo ṣe fi ìyà jẹ Jérúsálẹ́mù Kò sí èyí tí ó kéré jù nínú Júdà tí ó kù, tí ó ń gbé ilẹ̀ Éjíbítì tí yóò sá àsálà padà sórí ilẹ̀ Júdà, èyí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti padà sí, àti láti máa gbé àyàfi àwọn aṣàtìpó mèlòó kan Lẹ́yìn èyí, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ẹ bá mọ̀ pé, ìyàwó wọn sun tùràrí sí àwọn òrìṣà pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó bá wá àwọn ènìyàn púpọ̀, pàápàá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní òkè àti ìsàlẹ̀ Éjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni a wí fún Jeremáyà Wọn sì wí pé Àwa kò ní fetísílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o bá bá wa sọ ni orúkọ Olúwa Dájúdájú à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn Ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ni àwọn ìgboro Jérúsálẹ́mù Nígbà naà àwa ní ounjẹ púpọ̀ a sì ṣe rere a kò sì rí ibi Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí a ti dáwọ́ tùràrí sísun sí ayaba ọrun sílẹ̀ àti láti da ẹbọ ohun mímu fún un, àwa ti ṣaláìní ohun gbogbo, a sì run nípa idà àti nípa ìyàn Obìnrin náà fi kun-un pé, Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rúbọ si ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ Wàyí o, Jeremáyà sọ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, ọkùnrin àti obìnrin, tí wọn sì ń dáhùn pé, Ṣe Ọlọ́run kò rántí ẹbọ sísun ní ìlú Júdà àti àwọn ìgboro Jérúsálẹ́mù láti ọ̀dọ̀ rẹ àti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá rẹ, àwọn Ọba àti àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn ìlú Nígbà tí Ọlọ́run kò lè fi ara da ìwà búburú yín àti àwọn nǹkan ìbínú gbogbo tí ẹ ṣe, ilẹ̀ yín sì di ohun ìfiré àti ìkọ̀sílẹ̀, láìsí olùgbé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà lónìí Nítorí pé ẹ ti sun ẹbọ, tí ẹ sì ti ṣẹ̀ sí Olúwa àti pé ẹ kò gbọ́ràn síi lẹ́nu, àti pé ẹ kò sì tẹ̀lé òfin rẹ̀ àti àwọn àṣẹ Ibi náà yóò wá sórí rẹ àti bí o ṣe ríi Nígbà náà ni Jeremáyà dáhùn pẹ̀lú obìnrin náà pé, Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa , ẹ̀yin ọmọ Júdà tí ó wà ní Éjíbítì Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Ìwọ àti àwọn Ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ lórí sísun tùràrí àti dída ọtí sí orí ère ayaba ọ̀run ṣẹ Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ Ṣùgbọ́n gbọ ọ̀rọ̀ Olúwa , gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Éjíbítì, mo gégùn-ún Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa , wí pé, kò sí ẹnikẹ́ni láti Júdà tí ń gbé ibikíbi ní Éjíbítì ni tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láàyè Nítorí náà, mò ń wò wọ́n bí i fún ìparun, kì í ṣe fún rere Àwọn Júù tí ó wà ní Éjíbítì yóò parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi parun Àwọn tí ó bá sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìparun idà àti pípadà sí ilẹ̀ Júdà láti Éjíbítì yóò kéré níye Gbogbo àwọn tí ó bá kú ní ilẹ̀ Júdà, tí ó wá gbé ilẹ̀ Éjíbítì yóò mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò dúró yálà tèmi tàbí ti yín  Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún un yín pé èmi yóò fi ìyà jẹ yín níbi tí Olúwa ti sọ láti lè jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìjìyà mi tí mo sọ pé ẹ̀ ó jẹ yóò ṣẹ Báyìí ni Olúwa wí Èmi yóò fi Fáráò Hópírà Ọba Éjíbítì lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́, èyí tí ó lè pa ayé rẹ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekáyà Ọba Júdà lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lọ́wọ́ ọ̀tá tó ń lépa ẹ̀mí rẹ̀   Iṣẹ́ Rírán Sí Bárúkì Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà wòlíì sọ fún Bárúkì ọmọ Néríà ní ọdún kẹrin ti Jéhóíákímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà Lẹ́yìn tí Bárúkì ti kọ sínú ìwé kíká àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ti ń sọ Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ sí Bárúkì Ó wí pé, Ègbé ni fún mi! Olúwa fi kún ìṣòro tí mo ní mo di aláàbọ̀-ara pẹ̀lú ìrora àti àìní ìfọ̀kànbalẹ̀   Olúwa wí pé sọ èyí fún un, Èyí ni Ọlọ́run sọ Èmi yóò sí ipò àwọn ohun tí mo ti kọ àti pé Èmi yóò wú àwọn nǹkan tí mo gbìn sí orí ilẹ̀ náà Ṣé ìwọ yóò wá ohun rere fún ara rẹ Nítorí náà, má ṣe wá wọn Èmi yóò mú ibi wá sí orí àwọn ènìyàn gbogbo ni Olúwa wí Níbikíbi tí o bá lọ ni èmi yóò jẹ́ kí o sá àsálà ẹ̀mí rẹ ní àlàáfíà   Iṣẹ́ Nípa Éjíbítì Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremáyà wòlíì wá nípa Àwọn orílẹ̀ èdè Nípa Éjíbítì, Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ogun Fáráò Nékò Ọba Éjíbítì ẹni tí a borí rẹ̀ ní Káṣímísì, ní odò Ẹ́fúrétà láti ọwọ́ Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ní ọdún kẹrin Jéhóáíkímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà Pèsè ọ̀kọ̀ rẹ sílẹ̀, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré, kí o sì yan lọ síta fún ogun! Di ẹṣin ní gàárì, kí ẹ sì gùn ún Ẹ dúró lẹ́sẹsẹ pẹ́lú àsíborí yín! Ẹ dán ọ̀kọ̀ wò, kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin Kí ni nǹkan tí mo tún rí Wọ́n bẹ̀rù, wọ́n sì ń padà sẹ́yìn, wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun Wọ́n sá, wọn kò sì bojú wẹ̀yìn, ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo, ni Olúwa wí Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ, tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà Ní Gúṣù ní ibi odò Ẹ́fúrétà wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Náílì, tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n ọn nì Éjíbítì dìde bí odò náà, bí omi odò tí ń ru Ó sì wí pé, Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé Èmi yóò pa orílẹ̀ èdè àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin, ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́ Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú, ẹ̀yin ọkùnrin Kúṣì àti Pútì tí ń gbé ọ̀kọ̀ àti ẹ̀yin ọkùnrin Lìdíà tí ń fa ọrun Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀ Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn, títí yóò fi pa òrùngbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun yóò rúbọ ní ilẹ̀ Gúṣù ní odò Ẹ́fúrétà Gòkè lọ sí Gílíádì, kí o sì mú ìkunra, ìwọ wúndíá Éjíbítì Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn, kì yóò sí ìwòsàn fún ọ Àwọn orílẹ̀ èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ, igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ, àwọn méjèèjì yóò sì dìjọ ṣubú papọ̀ Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá Jeremáyà wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadinésárì Ọba Bábílónì láti lọ dojú ìjà kọ Éjíbítì Kéde èyí ní Éjíbítì, sì sọ ọ́ ní Nígídò, sọ ọ́ ní Mémífísì àti Táfánésì Dúró sí àyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀, nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú Wọn yóò máa ṣubú léraléra wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn Wọn yóò sọ wí pé, Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa, kúrò níbi idà àwọn aninilára Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé, Ariwo lásán ni Fáráò Ọba Éjíbítì pa, ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù Bí èmi ti wà láàyè, ni Ọba, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ ogun wí pé, nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tábórì láàrin àwọn òkè àti gẹ́gẹ́ bi Kámẹ́lì lẹ́bàá òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé Iwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé Éjíbítì pèsè ohun èlò ìrìn-àjò fún ara rẹ nítorí Nófù yóò di ahoro a ó sì fi jóná, láìní olùgbé Ẹgbọ̀rọ̀ abo màlúù tó lẹ́wà ní Éjíbítì ṣùgbọ́n eṣinṣin tí yóò le ń bọ̀ láti àríwá Àwọn jagunjagun rẹ̀ dàbí àbọ́pa màlúù Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà, wọn ó sì jùmọ̀ sá, wọn kò ní le dúró, Nítorí tí ọjọ́ ibi ńbọ̀ lórí wọn àsìkò láti jẹ wọ́n níyà Éjíbítì yóò pòṣé bí ejò tí ń sá bí ọmọ ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké, gẹ́gẹ́ bí i ti agégi Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀, ni Olúwa wí, nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀, nítorí pé wọ́n pọ̀ ju elẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye A ó dójú ti ọmọbìnrin Éjíbítì, a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé Èmi ṣetán láti fi ìyà jẹ Ámónì, òrìṣà Tíbísì, Fáráò Éjíbítì àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti àwọn Ọba rẹ̀ àti àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Fáráò Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Éjíbítì yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́, ni Olúwa wí Má bẹ̀rù, ìwọ Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi, má fòyà, ìwọ Ísírẹ́lì Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jínjìn, àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn Jákọ́bù yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò, kò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rù bà á Má bẹ̀rù, Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi, nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀ èdè run, láàrin àwọn tí mo fọ́n yín ká sí Èmi kò ní run yín tán Èmi yóò jẹ ọ́ níyà lórí òdodo, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀ láìjẹ ọ́ níyà Iṣẹ́ Nípa Awọn Ará Fílístínì Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tó tọ wòlíì Jeremáyà wá nípa àwọn Fílístínì, kí ó tó di pé Fáráò dojúkọ Gásà Báyìí ni Olúwa wí Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá, wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀ Wọn ò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀, ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn Àwọn ènìyàn yóò kígbe gbogbo ẹni tó ń gbé lórí ilẹ̀ yóò pohùnréré ẹkún Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró títẹlẹ̀ pátakò ẹsẹ̀ ẹṣin alágbára nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀tá ńlá àti iye kẹ̀kẹ́ wọn Àwọn baba kò ní lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ ọwọ́ wọn yóò kákò Nítorí tí ọjọ́ náà ti pé láti pa àwọn Fílístínì run, kí a sì mú àwọn tí ó là tí ó lè ran Tírè àti Sídónì lọ́wọ́ kúrò Olúwa ti ṣetán láti pa Fílístínì run, àwọn tí ó kù ní agbègbè Káfútò Gásà yóò fá irun orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀ A ó pa Áṣíkélónì lẹ́nu mọ́ ìyókù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ìwọ yóò ti ṣá ara rẹ lọ́gbẹ́ pẹ́ tó Ẹ̀yin kígbe, Yé è, idà Olúwa , yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò sinmi Padà sínú àkọ̀ re sinmi kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́ Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe sinmi, nígbà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un, nígbà tí ó ti pa á láṣẹ láti dojúkọ Áṣíkélónì àti agbégbé rẹ̀ Iṣẹ́ Nípa Móábù Nípa Móábù Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Ègbé ni fún Nébò nítorí a ó parun A dójú ti Kíríátaímù, a sì mú un, ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká Móábù kò ní ní ìyìn mọ́, ní Héṣíbónì ni wọn ó pète ìparun rẹ̀, Wá, kí a pa orílẹ̀ èdè náà run Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́, a ó fi idà lé e yín Gbọ́ igbe ní Horonáímù, igbe ìrora àti ìparun ńlá Móábù yóò di wíwó palẹ̀ àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta Wọ́n gòkè lọ sí Lúhítì, wọ́n ń sunkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ ní ojú ọ̀nà sí Horonáímù igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ Sá! Àsálà fún ẹ̀mí rẹ kí o dàbí igbó ní aṣálẹ̀ Níwọ̀n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ, a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn, Sémọ́sì náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀ Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ, ìlú kan kò sì ní le là Àfonífojì yóò di ahoro àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run, nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀ Fi iyọ̀ sí Móábù, nítorí yóò ṣègbé, àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀ Ìfibú ni fún ẹni tí ó dúró láti ṣe iṣẹ́ Olúwa , ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ Móábù ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá bí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀, tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejì kò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ, òórùn rẹ̀ kò yí padà Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, nígbà tí n ó rán àwọn tí ó da ọtí láti inú àwọn ìgò tí wọ́n ó sì dà á síta Wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo, wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀ Nígbà náà Móábù yóò sì tú u nítorí kémósì, bí ojú ti í ti ilé Ísírẹ́lì nígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Bétélì Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ajagun ni wá, alágbára ní ogun jíjà A ó pa Móábù run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀ a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀, ni Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ìṣubú Móábù súnmọ́ ìpọ́njú yóò dé kánkán Ẹ dárò fún, gbógbó ẹ̀yin tí ó yí i ká gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó Ẹ sọ pé, Báwo ni ọ̀pá agbára rẹ títóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́! Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ, kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ, ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Díbónì, nítorí tí ẹni tí ó pa Móábù run yóò dojúkọ ọ́ yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran, ìwọ tí ń gbé ní Áróà Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ Ojú ti Móábù nítorí tí a wó o lulẹ̀, ẹ hu, sì kígbe síta! Ámónì kéde pé a pa Móábù run Ìdájọ́ ti dé sí Pílátéù sórí Hólónì, Jáhásà àti Mẹ́fátì, sórí Díbónì, Nébò àti Bẹti Díbílátaímù sórí Kíríátaímù, Bẹti Gámù àti Bẹti Méónì, sórí Kéríótì àti Bóásì, sórí gbogbo ìlú Móábù, nítòsí àti ní ọ̀nà jínjìn A gé ìwo Móábù kúrò, apá rẹ̀ dá, ni Olúwa wí Ẹ jẹ́ kí a mú u mutí nítorí ó kó ìdọ̀tí bá Olúwa , jẹ́ kí Móábù pàfọ̀ nínú èébì rẹ̀, kí ó di ẹni ẹ̀gàn Ǹjẹ́ Ísírẹ́lì kò di ẹni ẹ̀gan rẹ Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olè tó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́ nígbákùúgbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrin àwọn òkúta, ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Móábù Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ẹnu ihò A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀ àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀ Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni, ni Olúwa wí, ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkankan Nítorí náà, mo pohùnréré ẹkún lórí Móábù fún àwọn ará Móábù ni mo kígbe lóhùn rara Mo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin Kíháráṣè Mo sunkún fún ọ bí Jásì ṣe sunkún ìwọ àjàrà Síbínà Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé òkun wọn, Ámónì, ajẹnirun ti kọlu èṣo rẹ àti àwọn èṣo àjàrà rẹ Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrò nínú ọgbà àjàrà àti oko Móábù, mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúnni kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ti ayọ̀ Ohùn igbe wọn gòkè láti Hésíbónì dé Élíà àti Jásì láti Sóà títí dé Hórónáímù àti Éjíbítì Sélíáyà, nítorí àwọn omi Nímírímù pẹ̀lú ti gbẹ Ní ti Móábù ni èmi yóò ti fi òpin sí ẹni tí ó rúbọ sí ibí gíga àti ẹni tí ń sun tùràrí fún òrìṣà rẹ̀, ni Olúwa wí Nítorí náà ọkàn mi ró fún Móábù bí fèrè oró Híhárésétì ìṣúra ńlá tí wọ́n kójọ ṣègbé Gbogbo orí mi ni ó pá, gbogbo irungbọ̀n ni a gé kúrò, gbogbo ọwọ́ ni a ṣá lọ́gbẹ́, àti aṣọ ọ̀fọ̀ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ Ní gbogbo orílẹ̀ èdè Móábù àti ní ita kò sí ohun kan bí kò ṣe ọ̀fọ̀, nítorí tí mo fọ́ Móábù bí a ti ń fọ́ ohun elò tí kò wu ni, ni Olúwa wí Èéṣe tí ẹ fi fọ́ túútúú, tí ẹ sì fi ń pohùnréré ẹkún! Báwo ni Móábù ṣe yí ẹ̀yìn padà ní ìtìjú! Móábù ti di ẹni ìtìjú àti ẹ̀gàn àti ìdààmú sí gbogbo àwọn tí ó yìí ká Báyìí ni Olúwa wí Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀ ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí Móábù Koríko kan yóò di kíkó àti àwọn ìlú olódì Ní ọjọ́ náà ọkàn akọni Móábù yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí A ó pa Móábù run gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè nítorípé ó gbéraga sí Olúwa Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Móábù, ní Olúwa wí Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fún ẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìn ẹnikẹ́ni tí o bá jáde síta nínú ọ̀fìn ní à ó mú nínú okùn dídè nítorí tí èmi yóò mú wá sórí Móábù àní ọdún Ìjìyà rẹ, ní Olúwa wí Ní abẹ́ òjìji Hésíbónì àwọn tí ó sá dúró láìní olùrànlọ́wọ́ nítorí iná ti jáde wá láti Hésíbónì àti ọwọ́ iná láti àárin Síónì sì jó iwájú orí Móábù run àti agbárí àwọn ọmọ àlùfáà Ègbé ní fún ọ Móábù! Wọn yóò sì kó àwọn ọmọkùnrin yín lọ sí ilẹ̀ àjèjì àti àwọn ọmọbìnrin yín lọ sí ìgbékùn Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ Móábù padà ní ọjọ́ ìkẹyìn, ni Olúwa wí Iṣẹ́ Nípa Ámónì Nípa ti Ámónì Ohun tí Olúwa sọ nìyìí Ísírẹ́lì kò ha ní ọmọkùnrin Ṣé kò ha ní àrólé bí Kí ló wá dé tí Mákómù fi jogún Gádì Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀ Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀, ni Olúwa wí nígbà tí èmi yóò mú ìdágìrì ogun bá Rábà tí Ámónì yóò sì di òkítì ahoro, gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná Nígbà náà ni Ísírẹ́lì yóò lé wọn, àwọn tí ó ti lé e jáde, ni Olúwa wí Pohùnréré ẹkún ìwọ Hésíbónì nítorí Áì tí rún, kígbe jáde ẹ̀yin ènìyàn Rábà, ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ Ẹ sáré sókè sódò nínú ọgbà nítorí Mákómù yóò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀ Kí ló dé tí ẹ fi ń fi àfonífojì yín yangàn Ẹ fi àfonífojì yín yangàn pẹ̀lú èṣo rere, ẹ̀yin ọmọbìnrin aláìsòótọ́ Gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé, ta ni yóò kò mí lójú Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹ láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká, ni Olúwa wí Olúwa àwọn ọmọ ogun Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì sí ẹnìkan tí yóò dá ìkólọ Ámónì padà, ni Olúwa wí Nípa Édómù Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temánì Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò, ìwọ tí ó ń gbé ní Dédánì nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Ísọ̀ ní àkókò tí èmi ó fìyà jẹ́ẹ́ Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀ Tí olè bá wá ní òru ǹjẹ́ wọn kò ní kó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́ Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Ísọ̀ sí ìhòòhò èmi kò ní bo ibi ìkọ̀kọ rẹ nítorí kí o máa baà fi ara rẹ pamọ́ Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti àwọn ará ilé rẹ yóò parun Wọn kò sì ní sí mọ́ Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀ èmi yóò dábòbo ẹ̀mí wọn Àwọn opó rẹ gan an lè gbékẹ̀lẹ́ mi Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ife náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà Ìwọ kò ní lọ láìjìyà ṣùgbọ́n ìwọ yóò mu un Èmi fi ara mi búra ni Olúwa wí, wí pé, Bósírà yóò bayé ara rẹ̀ jẹ́ Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ẹgún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé Èmi ti gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa A rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀ èdè láti sọ Ẹ kó ara yín jọ láti dojúkọ ọ́, ẹ dìde fún ogun Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrin orílẹ̀ èdè gbogbo ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn ènìyàn Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta tí o jòkó lórí ìtẹ́ gíga síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá, ni Olúwa wí Édómù yóò di ahoro gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sódómù àti Gòmórà pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká rẹ, ní Olúwa wí Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀ kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́ Bí kìnnìún ti ń bọ̀ láti igbó Jódánì wá sí pápá oko ọlọ́rà á èmi yóò lé Édómù láti ibi ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá Ta ni ẹni náà tí èmi yóò yàn fún èyí Ta lo dàbí èmi, ta ni ó le pè mí níjà Ta ni olùsọ́ àgùntàn náà tí ó lè dúró níwájú mi Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí Olúwa ní fún Édómù, ohun tí ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Témánì Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde Pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn Nípa ìṣubú ariwo wọn, ilẹ̀ yóò mì, a ó gbọ́ igbe wọn ní òkun pupa Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀, yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bóráṣà Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagun Édómù yóò dàbí ọkan obìnrin tí ń rọbí Nípa Dámásíkù Inú Hámátì àti Árípádì bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn, wọ́n sì dààmú bí omi òkun Dámásíkù di aláìlera, ó pẹ̀yindà láti sálọ, ìwárìrì sì dé bá a, ìbẹ̀rù àti ìrora dì í mú, ìrora bí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀ ìlú tí mo dunnú sí Lóòtọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ yóò ṣubú lójú pópó, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ yóò pa ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà, ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Èmi yóò fi iná sí odi Dámásíkù, yóò sì jó gbọ̀ngàn Bẹni-hádádì run Nípa Kédárì àti ìjọba Ásọ́rì èyí ti Nebukadinésárì Ọba Bábílónì dojú ìjà kọ Èyí ni ohun tí Olúwa sọ Dìde kí o sì dojú ìjà kọ kédárì, kí o sì pa àwọn ènìyàn ìlà oòrùn run Àgọ́ wọn àti agbo àgùntàn wọn yóò di gbígbà ilé wọn yóò di ìsínípò padà pẹ̀lú ẹrù àti ràkúnmí wọn Àwọn ọkùnrin yóò ké pè wọ́n Ìparun ní ibi gbogbo Sálọ kíákíá, dúró nínú ihò ìwọ tí ò ń gbé Ásórì, báyìí ni Olúwa wí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ti dojú ìjà kọ ọ́ Dìde kí o sì dojú ìjà kọ orílẹ̀ èdè kan pẹ̀lú ìrọ̀rùn, èyí tí ó dúró pẹ̀lú ìgboyà báyìí ní Olúwa wí Orílẹ̀ èdè tí kò ní yálà gbàgede tàbí irin, àwọn ènìyàn re ń dágbé Àwọn ràkunmí á di ẹrù àti àwọn agbo àgùntàn, wọ́n á di ìkógun Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́ Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo, báyìí ní Olúwa wí Ásọ́rì yóò di ibi ìdọdẹ àwọn akáta, ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé, kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀ Èyí ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èyí tí ó tọ Jeremáyà wòlíì wá nípa Élámù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekáyà Ọba Júdà Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára sọ Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Élámù, ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé lòdì sí Élámù Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rin àti pé, kò sí orílẹ̀ èdè tí ilẹ̀ àjèjì Élámù kò ní lọ Èmi yóò kẹ́gàn Élámù lójú àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń gbé Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn, pàápàá ìbínú gbígbóná mi bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn Èmi yóò sì pa Ọba wọn run àti olórí wọn, báyìí ni Olúwa wí Ṣíbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ Ẹ́lámù padà láìpẹ́ ọjọ́, báyìí ni Olúwa wí Kò Sí Ọ̀kan Tí Ó Jẹ́ Olóòótọ́ Lọ sókè àti sódò àwọn òpó Jérúsálẹ́mù Wò yíká, kí o sì mọ̀, kí o sì wá kiri Bí o bá le è rí ẹnìkan, tí ó jẹ́ olóòótọ́ àti olódodo, N ó dárí jìn ìlú yìí Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, Bí Olúwa ti ń bẹ, síbẹ̀ wọ́n búra èké Olúwa , ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́ Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n Ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ, wọ́n sì kọ̀ láti yípadà Èmi sì rò pé, talákà ni àwọn yìí wọn kò lóye nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà Olúwa , àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́ Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ, n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà Olúwa àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́ Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́, wọ́n sì ti já ìdè Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n, ìkokò ihà yóò sì pa wọ́n run, ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yín ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, nítorí àìgbọ́ràn yín pọ, apadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀ Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́ Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀ àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra Mo pèṣè fún gbogbo àìní wọn, síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbérè Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó, tí ó lágbára, wọ́n sì ń sunkún sí aya arákùnrin wọn Èmi kì yóò ṣàì fìyà jẹ wọ́n fún èyí ni Olúwa wí Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi lára irú orílẹ̀ èdè bí èyí bí Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run, ẹ má ṣe pa wọ́n run pátapáta Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ti jẹ́ aláìsòdodo sí mi, ni Olúwa wí Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ Olúwa wọ́n wí pé, Òun kì yóò ṣe ohun kan! Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́, ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run alágbára wí Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná, àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun Áà, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì, ni Olúwa wí, Èmi yóò mú kí orílẹ̀ èdè láti ọ̀nà jínjìn dìde sí i yín Orílẹ̀ èdè ìgbàanì àti alágbára nì àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ Àpò ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a sí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ, àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin, wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ, wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ Pẹ̀lú idà ni wọn ó run ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, ni Olúwa wí, Èmi kì yóò pa yín run pátapáta Àti pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì béèrè wí pé, Kí ni ìdí rẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo èyí sí wa Ìwọ yóò sì sọ fún wọn wí pé, Ẹ̀yin ti kọ̀mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin Ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín Nísinsìnyìí, ẹ̀yin yóò máa sin àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe ti yín Kéde èyí fún ilé Jákọ́bù, kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Júdà Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aláìlóye àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn, tí ó lójú ti kò fi ríran tí ó létí ti kò fi gbọ́ran Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi ni Olúwa wí Kò ha yẹ kí èyin ó wárìrì níwájú mi bí Mo fi yanrìn pààlà òkun, èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀ wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀ Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀, wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ Wọn kò sọ fún ara wọn pé, Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀, tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédéé Àìṣedéedée yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín Láàrin ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ, àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ, ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn Wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára, Wọ́n sanra wọ́n sì dán Ìwà búburú wọn kò sì lópin wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀ Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí ni Olúwa wí Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi lára orílẹ̀ èdè bí èyí bí Nǹkan ìbànújẹ́ àti ohun ìtara ti ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, àwọn àlùfáà sì ń ṣe àkóso pẹ̀lú àṣẹ ara wọn, àwọn ènìyàn mi sì nífẹ̀ẹ́ sí èyí, kí ni ẹ̀yin yóò ṣe ní òpin Iṣẹ́ Nípa Bábílónì Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi sẹ́nu Jeremáyà láti sọ fún ará ilẹ̀ Bábílónì Ẹ sọ ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ sì kéde, kí ẹ sì gbé àṣíà sókè Ẹ kede, ẹ má sì ṣe bòó wí pé, a kó Bábílónì, ojú tí Bélì, a fọ́ Merodákì túútúú, ojú ti àwọn ère rẹ̀, a fọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀ túútúú Àwọn ìlú ní apá àríwá yóò sì máa gbógun tì wọ́n Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóò sá kúrò ní ìlú yìí Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà, ni Olúwa wí, Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jùmọ̀ wá, àwọn, àti àwọn ọmọ Júdà, wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́ri Olúwa Ọlọ́run wọn Wọn ó máa bèèrè ọ̀nà Síhónì, oju wọn yóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayé-rayé, tí a kì yóò gbàgbé Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn sìnà, wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkè wọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré, wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹ àwọn ọ̀ta wọ́n sì wí pé, Àwa kò jẹ̀bi nítorí pé wọ́n ti sẹ̀ sí Olúwa ibùgbé òdodo àti ìrètí àwọn baba wọn Jáde kúrò ní Bábílónì fi ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì sílẹ̀ kí ẹ sì dàbí àgùntàn inú agbo tí à ń kó jẹ̀ Nítorí pé èmi yóò ru, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Bábílónì àwọn orílẹ̀ èdè ńlá láti ilẹ̀ àríwá Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀ Láti àríwá wá, à ó sì mú ọ Ọfà wọn yóò dàbí ọfà àwọn akọni alákíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo A ó dààmú Bábílónì, gbogbo àwọn tó dààmú rẹ yóò sì mú ìfẹ́ wọn sẹ, ni Olúwa wí Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀, ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìn fi ayọ̀ fò bí ẹgbọ̀rọ̀ màlúù sí koríko tútù, ẹsì ń yan bí akọ-ẹsin Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọ yóò sì gba ìtìjú Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀ èdè, ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti ihà tí kò lọ́ràá Nítorí ìbínú Olúwa , kì yóò ní olùgbé ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀ Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Bábílónì yóò fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀ Dúró sí àyè rẹ ìwọ Bábílónì àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ta ọfà náà Ẹ ta ọfà náà síi, nítorí ó ti sẹ̀ sí Olúwa Kígbe mọ-ọn ní gbogbo ọ̀nà! Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa , gbẹ̀san lára rẹ̀ Ṣe síi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmìíràn Mú kúrò ní Bábílónì olùgbìn àti olùkórè pẹ̀lú ohun ìkórè rẹ̀ Nítorí idà àwọn aninilára jẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, kí oníkálukú sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀ A ti fọ́n Ísírẹ́lì ká, Kìnnìún sì ti lé e lọ Ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ jẹ ẹ́ ni Ọba Ásíríà, ẹni tí ó sì jẹ eegun rẹ̀ kẹ́yìn ni Nebukadinésárì Ọba Bábílónì Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Ǹ ó fi ìyà jẹ Ọba Bábílónì àti ilẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ Ọba, Ásíríà Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Ísírẹ́lì padà wá pápá oko tútù rẹ̀ òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí kámẹ̀lì àti Básánì, a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè Éfúráímù àti ní Gílíádì Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, ni Olúwa wí, À ó wá àìṣedéédé ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n a ki yóò rí ìkankan àti ẹṣẹ Júdà a ki yóò sì rí wọn nítorí èmi yóò dáríjìn àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dásí Kọlu ilẹ̀ Mérátamù àti àwọn tí ó ń gbé ní Pékódì Kọlùú pa á, kí o sì párun pátapáta, ni Olúwa wí Ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún ọ Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà ìrọ́kẹ̀rẹ̀ ìparun ńlá Wo bi ilé ayé ti pín sí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ tó Wo bí Bábílónì ti di aláìlólùgbé ni àárin àwọn orílẹ̀ èdè Mo dẹ pàkúté sílẹ̀ fún ọ ìwọ Bábílónì, kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, o ti kó sínú rẹ̀ A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa Olúwa ti kó àwọn ohun èlò ìjà rẹ̀ jáde, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run ọmọ ogun ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Bábílónì Ẹ dìde sí láti ilẹ̀ jínjín párun pátapáta láìṣẹ́kù Pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn rẹ̀, jẹ́ kí a kó wọn lọ ibi tí a ó ti pa wọ́n! Ègbé ní fún wọn! Nítorí ọjọ́ wọn dé, àkókò ìbẹ̀wò wọn Tẹ́tí sí àwọn tí ó sálọ tí ó sì sálà láti Bábílónì, sì sọ ní Síónì, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san, ẹ̀san fún tẹ́ḿpílì rẹ̀ Pe ọ̀pọ̀lopọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Bábílónì, ẹ doti iyikakiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi gbógbó èyí ti o ti ṣé, ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ síi, nítorí tí ó ti gberaga sí Olúwa , sí Ẹni-MÍMỌ̀ Ísirẹ́lì Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn ológun lẹ́nu mọ́, ní Olúwa wí Wò ó, èmi lòdì sí àwọn onígbéraga, ni Olúwa Ọlọ́run, ọmọ ogun wí, nítorí ọjọ́ rẹ ti dé tí ìwọ yóò jìyà Onígbéraga yóò kọsẹ̀, yóò sì ṣubú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò gbé dìde Èmi yóò tan iná ní ìlú náà, èyí tí yóò sì jo run Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára sọ A pọ́n àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lójú àti àwọn ènìyàn Júdà pẹ̀lú Gbogbo àwọn tí ó kó wọn nígbèkùn dì í mú ṣinṣin wọn kò sì jẹ́ kí ó sá àsálá Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára, Olúwa Ọlọ́run alágbára ni orúkọ rẹ̀ Yóò sì gbe ìjà wa jà, kí ó ba à lè mú wọn wá sinmí ní ilẹ̀ náà àmọ́ kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Bábílónì Idà lórí àwọn Bábílónì! ni Olúwa wí, lòdì sí àwọn tó ń gbé ní Bábílónì, àwọn aláṣẹ àti àwọn amòye ọkùnrin Idà lórí àwọn wòlíì èké wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun, wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ àti àwọn àjòjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀ Wọn yóò di obìnrin Idà lórí àwọn ohun ìṣura rẹ̀! Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀ yóò sì gbẹ Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère, àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù Nítorí náà àwọn ẹranko ijù pẹ̀lu ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀, abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀, a kì ó sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé, bẹ́ẹ̀ ni a kì ó ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọba Sódómù àti Gòmórà pẹ̀lú àwọn ìlú agbégbé wọn, ni Olúwa wí, kì yóò sí ẹni tí yóò gbé ibẹ̀ Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ ogun láti ìhà àríwá orílẹ̀ èdè ńlá àti àwọn Ọba pípọ̀ ni à ń gbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun, wọ́n burú wọn kò sì ní àánú Wọ́n bú bí i rírú omi bí wọ́n ti se ń gun ẹsin wọn lọ Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì Ọba Bábílónì ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wọn sì rọ, ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí Bí i kìnnìún tí ń bú láti igbó Jọ́dánì N ó lé Bábílónì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kánmọ́ kánmọ́ Ta ni ẹni àyànfẹ́ náà tí n ó yàn Ta ló dàbí mi, ta ló dàbí mi, ta ló sì le dojú ìjà kọmí Nítorí náà, gbọ́ ohun tí Olúwa sọ nípa Bábílónì ẹni tí ó gbìmọ̀ lòdì sí Bábílónì n ó sì pa agbo ẹran wọn run Ní dídún fèrè Bábílónì gbogbo ilẹ̀ ayé yóò mì tìtì igbe rẹ̀ yóò sì búja gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè Ohùn ti Olúwa nìyìí wò ó èmi yóò ru ẹ̀mí apanirun kan sókè sí Bábílónì àwọn ènìyàn Lébíkámáì Èmi yóò rán àwọn àjèjì ènìyàn sí Bábílónì láti ba ilẹ̀ jẹ́, wọn yóò ṣe àtakò rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà ní ọjọ́ ìparun rẹ̀ Má ṣe jẹ́ kí tafàtafà yọ ọfà rẹ̀ jáde tàbí kí o di ìhámọ́ra rẹ̀ má ṣe dá àwọn ọdọ́mọkùnrin sí, pátapáta ni kí o pa àwọn ọmọ ogun rẹ̀ Gbogbo wọn ni yóò ṣubú ní Bábílónì tí wọn yóò sì farapa yánna yànna ní òpópónà Nítorí pé Júdà àti Ísírẹ́lì ni Ọlọ́run wọn tí í se Olúwa alágbára kò gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ilé wọn kún fún kìki ẹ̀bi níwájú ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì Sá kúrò ní Bábílónì! Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe ṣègbé torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ Àsìkò àti gbẹ̀san Ọlọ́run ni èyí, yóò sán fún òun gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ Ifẹ́ wúrà ni Bábílónì ní ọwọ́ Olúwa ó sọ gbogbo ayé di ọ̀mùtí Gbogbo orílẹ̀ èdè mu ọtí rẹ̀, wọ́n sì ti ya òmùgọ̀ kalẹ̀ Bábílónì yóò ṣubú lójijì, yóò sì fọ́ sunkún fún un! Wá báàmù fún ìrora rẹ, bóyá yóò le wo ọ́ sàn  À bá ti wo Bábílónì sàn, ṣùgbọ́n kò lè sàn, ẹ jẹ́ kí a fi sílẹ̀, kí oníkálùkù lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ torí ìdájọ́ rẹ̀ tó gòkè, ó ga àní títí dé òfurufù   Olúwa ti dá wa láre, wá jẹ́ kí a sọ ọ́ ní Síónì ohun tí Olúwa Ọlọ́run wa ti ṣe Lọ ọfà wa kó mú, mú apata! Olúwa ti ru Ọba Médíà sókè, nítorí pé ète rẹ̀ ni láti pa Bábílónì run Olúwa yóò gbẹ̀san, àní ẹ̀san fún Tẹ́ḿpìlì rẹ̀ Gbé àsìá sókè sí odi Bábílónì! Ẹ ṣe àwọn ọmọ ogun gírí, ẹ pín àwọn olùsọ́ káàkiri, ẹ ṣètò àwọn tí yóò sápamọ́ Olúwa ! Yóò gbé ète rẹ̀ jáde, òfin rẹ̀ sí àwọn ará Bábílónì Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀, tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀ ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé, àní àsìkò láti ké ọ kúrò! Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra fún ara rẹ̀, Èmi yóò fún ọ ní ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ eṣú, wọn yóò yọ ayọ̀, iṣẹ́gun lórí rẹ Ó dá ilẹ̀ nípa agbára rẹ̀, o dá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, o sì tẹ́ ọ̀run pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀ Nígbà tí ará omi ọ̀run hó ó mú kí òfùrufú ru sókè láti ìpẹ̀kun ayé Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti ilé ìṣúra rẹ̀ Olúkúlùkù ènìyàn ni kò lọ́pọlọ tí kò sì ní ìmọ̀, olúkùlúkù alágbẹ̀dẹ ni a kó ìtìjú bá nípa òrìṣà rẹ̀ Àwọn ère rẹ jẹ́ ẹ̀tàn wọn kò ní èémí nínú Wọn kò já mọ́ nkànkan, wọ́n jẹ́ ohun ẹlẹ́yà nígbà tí ìdájọ́ wọn bá dé, wọn ó ṣègbé Ẹni tí ó jẹ́ ìpín Jákọ́bù kó rí bí ìwọ̀nyí nítorí òun ni ó dá ohun gbogbo, àti gbogbo àwọn ẹ̀yà ajogún, Olúwa alágbára ni orúkọ rẹ̀ Ìwọ ni kùmọ̀ ohun èlò ogun mi, ohun èlò ìjà mi, pẹ̀lú rẹ èmi ó fọ́ orílẹ̀ èdè túútúú, èmi ó bà àwọn ilé Ọba jẹ́ Pẹ̀lú rẹ, èmi ó pa ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún pẹ̀lú rẹ̀ èmi ó ba kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ pẹ̀lú èmi ó pa awakọ̀ Pẹ̀lú rẹ, mo pa ọkùnrin àti obìnrin, pẹ̀lú rẹ, mo pa àgbàlagbà àti ọmọdé, Pẹ̀lú rẹ, mo pa ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin Pẹ̀lú rẹ, mo pa olùsọ́ àgùntàn àti agbo àgùntàn rẹ̀ pẹ̀lú rẹ, mo pa àgbẹ̀ àti màlúù, Pẹ̀lú rẹ, mo pa gómìnà àti àwọn alákòóṣo ìjọba rẹ̀ Ní ojú rẹ, èmi yóò san án fún Bábílónì àti gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ fún gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe ní Síónì, ni Olúwa wí Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirun ìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́, ni Olúwa wí Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ, èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta, Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó A kò ní mú òkúta kankan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbí fún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò di ahoro títí ayé, ní Olúwa wí Gbé àṣíá sókè ní ilẹ̀ náà, fọn ipe láàrin àwọn orílẹ̀ èdè! Pèṣè àwọn orílẹ̀ èdè sílẹ̀ láti bá jagun, pe àwọn ìjọba yìí láti doju kọ ọ́, Árárátì, Mínínì àti Ásíkẹ́nì Yan olùdarí ogun láti kọlù ú, rán àwọn ẹṣin síi bí ọ̀pọ̀ eṣú Pèsè àwọn orílẹ̀ èdè láti bá jagun, àwọn Ọba Médíà, Gómìnà àti gbogbo ọmọ ìgbìmọ̀ wọn àti gbogbo orílẹ̀ èdè tí wọ́n jọba lé lórí Ilẹ̀ wárìrì síhìn ín sọ́hùn ún, nítorí pé ète Olúwa , sí Bábílónì dúró láti ba ilẹ̀ Bábílónì jẹ́ lọ́nà tí ẹnikẹ́ni kò ní lè gbé inú rẹ̀ mọ́ Gbogbo àwọn jagunjagun Bábílónì tó dáwọ́ ìjà dúró la sí àgọ́ wọn Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun, gbogbo irin ẹnu ọ̀nà wọn ti di fífọ́ Iránsẹ́ kan ń tẹ̀lé òmíràn láti sọ fún Ọba Bábílónì pé gbogbo ìlú rẹ̀ ni a ti kó ní ìgbèkùn Odò tí ó ṣàn kọjá kò ṣàn mọ́ ilẹ̀ àbàtà gbiná, àwọn jagunjagun sì wárìrì Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ nìyìí Ọmọbìnrin Bábílónì dàbí ìpakà àsìkò láti kórè rẹ̀ kò ní pẹ́ dé mọ́ Nebukadinésárì Ọba Bábílónì tó jẹ wá run, ó ti mú kí ìdààmú bá wa, ó ti sọ wá di àgbá òfìfo Gẹ́gẹ́ bí ejò, ó ti gbé wa mì Ó fi oúnjẹ àdídùn wa kún inú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni Ó pọ̀ wá jáde Kí gbogbo ìparun tí ó ṣe sí ẹran ara wa wà lórí Bábílónì èyí tí àwọn ibùgbé Síónì wí Kí ẹ̀jẹ̀ wa wà lórí gbogbo àwọn tí ń gbé Bábílónì, ni Jérúsálẹ́mù wí Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí Wò ó, èmi yóò tì ọ́ lẹ́yìn lórí ohun tí o fẹ́ ṣe Èmi ó sì gbẹ̀san, èmi yóò mú kí omi òkun rẹ̀ àti orísun omi rẹ̀ gbẹ Bábílónì yóò parun pátapáta, yóò sì di àwọn akáta, ohun ẹ̀rù àti àbùkù, ibi tí ènìyàn kò gbé Àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ramúramù bí ọmọ kìnìún Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn wọn bá ru sókè, èmi yóò se àsè fún wọn, èmi yóò jẹ́ kí wọn mutí yó débi tí wọn yóò máa kọ ẹ̀rín lẹ́yìn náà, wọn yóò sun oorun àsùnjí, ni Olúwa wí Èmi yóò fà wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ àgùntàn tí a fẹ́ pa, gẹ́gẹ́ bí àgbò àti ewúrẹ́ Bí Sésákì yóò ṣe dí mímú, ìfọ́nnu gbogbo àgbáyé Irú ìpàyà wo ni yóò bá Bábílónì láàrin àwọn orílẹ̀ èdè! Òkun yóò ru borí Bábílónì, gbogbo rírú rẹ̀ yóò borí Bábílónì Àwọn ìlú rẹ̀ yóò di ahoro, ilẹ̀ tí ó gbẹ, ilẹ tí ènìyàn kò gbé tí ènìyàn kò sì rin ìrìnàjò Èmi yóò fi ìyà jẹ Bélì ti Bábílónì àti pé èmi yóò jẹ́ kí ó pọ gbogbo àwọn ohun tí ó gbé mì Orílẹ̀ èdè kò ní i jẹ́ ìṣàn fún-un mọ́ Odi Bábílónì yóò sì wó Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn mi! Sá àṣálà fún ẹ̀mi rẹ! Sá fún ìbínú ńlá Ọlọ́run Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ dàrú tàbí kí o bẹ̀rù nígbà tí a bá gbọ àhesọ ọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ wa àhesọ ọ̀rọ̀ kan wá ní ọdún yìí, òmíràn ní ọdún mìíràn àhesọ ọ̀rọ̀ ni ti ìwà ipá ní ilẹ̀ náà àti tí aláṣẹ kan sí aláṣẹ kejì Nítorí ìgbà náà yóò wá dandan nígbà tí èmi yóò fi ìyà jẹ àwọn òrìṣà Bábílónì, gbogbo ilẹ rẹ̀ ni a ó dójú tì gbogbo àwọn tí a pa yóò sì ṣubú ní àárin rẹ̀ Ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn, yóò sì kọrin lórí Bábílónì nítorí àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sórí rẹ̀ láti àríwá, ni Olúwa wí Gẹ́gẹ́ bí Bábílónì ti mú kí àwọn olùpa Ísírẹ́lì ṣubú bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní àwọn olùpa gbogbo ilẹ̀ ayé yóò ṣubú Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè, ẹ sì jẹ́ kí Jérúsálẹ́mù wá sí ọkàn yín Ojú tì wá, nítorí pé àwa ti gbọ́ ẹ̀gàn ìtìjú ti bò wá lójú nítorí àwọn àlejò wá sórí ohun mímọ́ ilé Olúwa Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí èmi yóò se ìbẹ̀wò lórí àwọn ère fífin rẹ̀ àti àwọn tí ó gbọgbẹ́ yóò sì máa gbin já gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ Bí Bábílónì tilẹ̀ gòkè lọ sí ọ̀run, bí ó sì ṣe ìlú olodi ní òkè agbára rẹ, síbẹ̀ àwọn afiniṣèjẹ yóò ti ọ̀dọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá, ní Olúwa wí Ìró igbe láti Bábílónì, àti ìparun láti ilẹ̀ àwọn ará Kálídéà! Nítorí pé Olúwa ti ṣe Bábílónì ní ìjẹ, ó sì ti pa ohun ńlá run kúrò nínú rẹ̀ rírú wọn sì ń hó bi púpọ̀, a gbọ́ ariwo ohùn wọn Nítorí pé afiniṣe ìjẹ dé sórí rẹ̀, àní sórí Bábílónì a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni Olúwa , yóò san án nítòótọ́ Èmi ó sì mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ yó bí ọ̀mùtí, àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ àti àwọn alákòóṣo rẹ̀, àti àwọn akọni rẹ̀, wọn ó sì sun oorun láéláé, wọn kì ó sì jí mọ́, ní Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa ọmọ ogun Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Odi Bábílónì gbígbòòrò ní a ó wó lulẹ̀ pátapáta, ẹnu bodè gíga rẹ̀ ní a ó sì fi iná sun tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ṣiṣẹ́ lásán, àti àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣiṣẹ́ fún iná, tí àárẹ̀ sì mú wọn Ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà wòlíì pàṣẹ fún Seráíyà, ọmọ Néríà, ọmọ Mááséíyà, nígbà tí o ń lọ ni ti Ṣedekáyà, Ọba Júdà, sí Bábílónì ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀ Séráíà yí sì ní ìjòyè ibùdó Jeremáyà sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ ibi tí yóò wá sórí Bébálì sínú ìwé kan, àní gbogbo ọ̀rọ wọ̀nyí tí a kọ sí Bábílónì Jeremáyà sì sọ fún Séráíà pé, nígbà tí ìwọ bá dé Bábílónì, kí ìwọ kí ó sì wò, kí ìwọ kí ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí Kí ìwọ kí ó sì wí pé, Olúwa ìwọ ti sọ̀rọ̀ sí ibí yí, láti ké e kúrò, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀, àti ènìyàn àti ẹran, nítorí pé yóò di ahoro láéláé Yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá parí kíka ìwé yìí tán kí ìwọ kí ó di òkúta mọ́ ọn, kí ó sì sọ ọ́ sí àárin odò Éfúrétè Kí ìwọ sì wí pé, Báyìí ní Bábílónì yóò rì, kí yóò sì tún dìde kúrò nínú ibi tí èmi ó mú wá sórí rẹ̀ àárẹ̀ yóò sì mú wọn   Títí dé ìhín nií ọ̀rọ̀ Jeremáyà Ìṣubú Jérúsálẹ́mù Ṣédékáyà jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó jẹ Ọba Ọdún mọ́kànlá ló fi jọba ní Jérúsálẹ́mù Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútalì ọmọ Jeremáyà láti Líbíná ló ti wá Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa gẹ́gẹ́ bí Jéhóáikímù ti ṣe Nítorí ìbínú Olúwa ni gbogbo èyí ṣe ṣẹlẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà àti ní ìkẹyìn Ó sì gbà wọ́n gbọ́ ní iwájú rẹ̀ Sedekáyà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọba Bábílónì Nígbà tí ó di ọdún kẹ́sàn án ti Sedekáyà tí ń ṣe ìjọba ní ọjọ́ kẹ́wàá, oṣù kẹ́wàá Nebukadinésárì Ọba Bábílónì sì lọ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà wọ́n sì mọ odi yíká rẹ̀ Ìlú náà sì wá lábẹ́ ìhámọ́ títí di ọdún kọkànlá Ọba Sédékáyà Ní ọjọ́ kẹ́sàn án, oṣù mẹ́rin ìyàn ìlú náà sì ti burú dé ibi pé kò sí oúnjẹ kankan mọ́ fún àwọn ènìyàn láti jẹ Bákan náà, odi ìlú náà ti ya àwọn ọmọ ogun sì tí sálọ Wọn fi ìlú náà sílẹ̀ ní òru nípa ojú ọ̀nà tó wà láàrin odi méjèèjì lẹ́bàá ọgbà Ọba Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Àwọn ará Bábílónì yìí yí ìlú náà ká Wọ́n sá gba aginjù lọ Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ogun Bábílónì lépa Ọba Sedekáyà wọ́n sì le bá ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì pínyà, kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ wọ́n sì túká Wọ́n sì mu ní ìgbèkùn Wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba Bábílónì, ní Ríbíla ní ilẹ̀ Hámátì níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀ Ní Ríbílà ni Ọba Bábílónì ti pa ọmọkùnrin Sedekáyà lójú rẹ̀ ó sì tún pa gbogbo àwọn aláṣẹ Júdà Lẹ́yìn náà, o yọ ojú Ṣedekáyà síta, o sì fi ẹ̀wọ̀n yìí dì í, ó sì gbe e lọ sí Bábílónì níbi tí ó ti fi sínú ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n títí di ikú ọjọ́ rẹ̀ Ní ọjọ́ kẹ́wàá oṣù kárùn-ún ní ọdún kọkàndínlógún Ọba Nebukadinésárì ti Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù Ó dáná sun pẹpẹ Olúwa , ààfin àti gbogbo àwọn ilé Jérúsálẹ́mù Ó sì dáná sun gbogbo àwọn ilé ńláńlá Gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí wọ́n wà lábẹ́ àṣẹ balógun ìṣọ́ wó gbogbo odi tí ó yí ìlú Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ Nebusarádánì balógun ìsọ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú náà lọ sí ilẹ̀ àjèjì pẹ̀lú àwọn oníṣọ̀nà tí ó kù àti gbogbo àwọn tí ó ti lọ sọ́dọ̀ Ọba Bábílónì Ṣùgbọ́n Nebukadinésárì fi àwọn tálákà tó kú ní ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà àti oko Àwọn Bábílónì fọ́ idẹ ìpìlẹ̀ àti àwọn ìjókòó tó ṣe é gbé kúrò àti àwọn ìdè wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní pẹpẹ Olúwa Wọ́n sì kó gbogbo idẹ náà lọ sí Bábílónì Bákan náà, wọ́n tún kó àwọn ìkòkò, ọkọ́ àti ọ̀pá fìtílà, àwọn ọpọ́n, síbí àti gbogbo ohun èlò idẹ tí wọ́n ń lò níbi pẹpẹ lọ Balógun àwọn ìṣẹ́ náà kó àwokòtò, ohun ìfọná, ọpọ́n ìkòkò, ọ̀pá fìtílà, síbí àti ago wáìnì èyí tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ Àwọn ọ̀wọ̀n méjì agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbèéká tí ó ṣe fún ibi pẹpẹ Olúwa , èyí tí ó kọjá èyí tí a lè gbéléwọ̀n Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọ̀wọ̀n yìí ni o nà mí, ìwọn ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún tí fífẹ̀ rẹ̀ sì tó ìgbọ̀nwọ́ méjìlá Ọ̀kọ̀ọ̀kan nípọn tó ìka mẹ́rin, wọ́n sì ní ihò nínú Ọ̀nà orí idẹ kan tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, wọ́n sì fi èṣo pomegiranátì ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára yíká Ọ̀wọ́n kejì sì wà pẹ̀lú èṣo pomegiranátì tí ó jọra Pomegiranátì mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni ó wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ Àpapọ̀ gbogbo pomegiranátì sì jẹ́ ọgọ́rùn ún kan Balógun àwọn ẹ̀sọ́ mu Ṣeráyà olórí àwọn àlùfáà àti Ṣefanáyà tí ó jẹ́ igbá kejì rẹ̀ àti gbogbo àwọn asọ́nà Nínú àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, ó mú alásẹ tí ó wà ní ìtọ́jú àwọn ológun, àti àwọn olùdámọ̀ràn Ọba méje Bákan náà, ó tún mu akọ̀wé olórí ogun tí ó wà ní ìtọ́jú títo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọgọ́ta nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú náà Nebusaradánì balógun náà kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn lọ sọ́dọ̀ Ọba Bábílónì ní Ríbílà Ní Ríbílà ni ilẹ̀ Hámátì Ọba náà sì pa wọ́n Báyìí ni Júdà sì sá kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ Èyí ni iye àwọn ènìyàn tí Nebukadinésárì kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì Ní ọdún keje ẹgbẹ̀dógún ó lé mẹ́talélógún ará Júdà Ní ọdún kejìdínlógún Nebakadinésárì o kó ẹgbẹ̀rún ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n láti Jérúsálẹ́mù Ní ọdún kẹtàlélógún ènìyàn Júù tí Nebukadinésárì kó lọ sí ilẹ̀ àjòjì jẹ́ márùn ún Gbogbo ènìyàn tí ó kó lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún Ní ọdún kẹtàdín lógójì ti Jéhóáíkímù Ọba Júdà ni Efili-merodaki di Ọba Bábílónì Ó tú Jéhóáíkímù Ọba Júdà sílẹ̀ nínú túbú ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kéjìlá Ó ń sọ̀rọ̀ rere sí i, ó sì fún un ní ìjókòó ìgbéga, èyí tí ó ju ti àwọn Ọba yóòkù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì Nítorí náà, Jéhóáíkímù bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n rẹ̀ ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ fún ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀ Ó sì ń jẹun lórí àga Ọba Ní ojoojúmọ́ ni Ọba Bábílónì ń fún Jéhóáíkímù ní ìpín tirẹ̀ títí ọjọ́ ayé rẹ̀ tí ó fi kú Jérúsálẹ́mù Lábẹ́ Ìgbékùn Ẹ̀yin ènìyàn Bẹ́ńjámínì, sá síbi ààbò! Ẹ sá kúrò ní Jérúsálẹ́mù, Ẹ fọn fèrè ní Tékóà! Kí ẹ gbé àmì sókè lórí Bẹti-Ákérémù! Nítorí àjálù farahàn láti àríwá, àní ìparun tí ó lágbára Èmi yóò pa ọmọbìnrin Síónì run, tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́ Olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbógun tì wọ́n Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká, olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀ Múra sílẹ̀ láti bá a jagun! Dìde, kí a kọ lù ú ní ìgbà ọ̀sán! Àmọ́ ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán, ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọ lù ú ní àṣálẹ́ kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́ Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀ kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jérúsálẹ́mù ká A gbọdọ̀ fi ìyà jẹ orílẹ̀ èdè yìí nítorí pé ó kún fún ìrẹ́nijẹ Gẹ́gẹ́ bí kàǹga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀, náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde Ìwà ipá àti ìparun ń tún dún padà nínú rẹ̀ nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi Ìwọ Jérúsálẹ́mù, gba ìkìlọ̀ kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro, tí kò ní ní olùgbé Èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí Jẹ́ kí wọn pesẹ́ ìyókù Ísírẹ́lì ní tónítóní bí àjàrà na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èṣo àjàrà jọ Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi Etí wọn ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́ Ọ̀rọ̀ Olúwa , jẹ́ ohun búburú sí wọn, wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀ Èmi kún fún ìbínú Olúwa , èmi kò sì le è pa á mọ́ra Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àti sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kóra wọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a ò mú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbó tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn, oko wọn àti àwọn aya wọn, nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà, ni Olúwa wí Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè, àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀ sì kún fún ẹ̀tàn Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi bí ẹni pé kò tó nǹkan Wọ́n ń wí pé, Àlàáfíà, Àlàáfíà, nígbà tí kò sì sí àlàáfíà Ojú há a tì wọ́n nítorí ìwà ìríra wọn bí Rárá, wọn kò ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní ooru ìtìjú Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrin àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn lulẹ̀ nígbà tí mo bá fìyà jẹ wọ́n ni Olúwa wí Èyí ni ohun tí Olúwa wí Ẹ dúró sí ìkòríta, kí ẹ sì wò, ẹ bere fún ipa ìgbàanì, ẹ bèèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ sì wọ inú rẹ, ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, Àwa kì yóò rin nínú rẹ Èmi yan olùsọ́ fún un yín, mo sì wí pé Tẹ́tí sí dídún fèrè náà, ẹ̀yìn wí pé, Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀ Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè kíyèsí, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí ohun tí yóò sẹlẹ̀ sí wọn Gbọ́, ìwọ ayé! Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, eṣo ìrò inú wọn, nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀ Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti ṣébà wá, tàbí eso dáradára láti ilẹ̀ jínjìn réré Ọrẹ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ẹbọ yín kò sì wù mí Nítorí náà, èyi ni ohun tí Olúwa wí Èmi yóò gbé ohun ìdènà ṣíwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí, àwọn bàbá àti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n, àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé Èyí ni Olúwa wí Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá, a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìde láti òpin ayé wá Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀, Wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú wọ́n ń hó bí omi òkun, bí wọ́n ti ṣe ń gun àwọn ẹsin wọn lọ wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò jà ọ́ lógun, ìwọ ọmọbìnrin Síónì Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa bí ìrora bí obìnrin tí í rọbí Má ṣe jáde lọ sí orí i pápá tàbí kí o máa rìn ní àwọn ojú ọ̀nà, nítorí ọ̀tá náà ní idà, ìpayà sì wà níbi gbogbo Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé asọ ọ̀fọ̀ wọ̀, kí ẹ sì sùn nínú eérú, ẹ sọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín, kanṣoṣo nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́ irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin tútù, kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí, kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀ òdì Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin, wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́ Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkán, kí ó lè yọ́ òjé, ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán a ko si ya ènìyàn búburú kúrò A pè wọ́n ní fàdákà tí a kọ̀ sílẹ̀, nítorí Olúwa ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ Ẹ̀sìn Àìsòótọ́ Kò Ní Láárí Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jérémáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Dúró ní ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yí  Ẹgbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀yin ará Júdà tí ń gba ọ̀nà yí wọlé láti wá sin Olúwa Èyi ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Tún àwọn ọ̀nà yín ṣe, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ gbé ilẹ̀ yìí Má ṣe gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn gbọ́ kí ẹ sì wí pé, Èyí ni ilé Tẹ́ḿpìlì Olúwa ilé Tẹ́ḿpìlì Olúwa , ilé Tẹ́ḿpìlì Olúwa ! Bí ẹ̀yin bá tún ọ̀nà yín àti ìṣẹ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ sì ń bá ara yín lò ní ọ̀nà tó tọ́ Bí ẹ kò bá fi ara ni àwọn àlejò, àwọn ọmọ aláìní baba àti àwọn opó tí ẹ kò sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, bí ẹ kò bá sì tọ Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn sí ìpalára ara yín Nígbà náà ni èmi yóò jẹ́ kí ẹ gbé ìbí yìí, nílẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín títí láé Ẹ wò ó, Ẹ̀ ń gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò níláárí gbọ́  Ẹ̀yin yóò ha jalè, kí ẹ pànìyàn, kí ẹ se pánṣágà, kí ẹ búra èké, kí ẹ sun tùràrí sí Báálì, kí ẹ sì tọ Ọlọ́run mìíràn tí ẹ̀yin kò mọ̀ lọ Nígbà náà ni kí ó wá dúró ní iwájú nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, Kí ẹ wá wí pé àwa yè, sé yíyè láti ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìnira wọ̀nyí bí Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́sà lọ́dọ̀ yín ni Èmi ti ń wò ó! ni Olúwa wí  Ẹ lọ nísinsìn yìí sí ṣílò níbi ti mo kọ́ fi ṣe ibùgbé fún orúkọ mi, kí ẹ sì rí ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú Ísírẹ́lì tí í ṣe ènìyàn mi Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni Olúwa wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn Nítorí náà, èmi yóò ṣe ohun tí mo ṣe sí ṣílò sí ilé náà tí a fi orúkọ mi pè, ilé Tẹ́ḿpìlì nínú èyí tí ẹ ní ìgbàgbọ́, àyè tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba yín Èmi yóò tú kúrò ní iwájú mi gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí àwọn arákùnrin yín, àwọn ará Éfúráímù Nítorí náà má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn ma ṣe bẹ̀ mí, nítorí èmi kì yóò tẹ́tí sí ọ Ṣé ìwọ kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ní òpópó Jérúsálẹ́mù Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná síi, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn Ọlọ́run àjòjì láti mú mi bínú sókè Ṣùgbọ́n ṣe èmi ni wọ́n fẹ́ mú bínú ni Olúwa wí Ǹjẹ́ kì í ṣe pé wọ́n kúkú ń pa ara wọn lára sí ìtìjú ara wọn  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí Èmi yóò tú ìbínú àti ìrunú mi sí orílẹ̀ yìí ènìyàn àti ẹranko, igi, pápá àti èṣo orí ilẹ̀, yóò sì jó tí kò ní ṣe é pa  Èyí ni Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí Tẹ̀ṣíwájú kí ẹ kó ẹbọ sísun yín àti àwọn ẹbọ yóòkù papọ̀ kí ẹ̀yin kí ó sì jẹ ẹran wọ́n fúnra yín Ní tòsí nígbà tí mo mú àwọn baba-ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì tí mo sì bá wọn sọ̀rọ̀ N kò pàṣẹ fún wọn lórí ẹbọ sísun lásán Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé Gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi Má a rìn ní ojú ọ̀nà tí mo paláṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, wọn kò sì fetí sílẹ̀ dípò èyí wọ́n ń tẹ̀ sí ọ̀nà agídí ọkàn wọn Dípò kí wọn tẹ̀ṣíwájú wọ́n ń rẹ̀yìn Láti ìgbà tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní Éjíbítì títí di òní, ni èmi ti ń rán àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì sí yín Wọn kò gbọ́ wọn kò sì fetísílẹ̀ Wọ́n wa ọrùn le, wọn wa ọrùn kì, wọ́n sì hu ìwà ìbàjẹ́ ju àwọn baba ńlá wọn Nígbà tí wọ́n bá sọ gbogbo èyí fún wọn, wọn kì yóò gbọ́ tirẹ̀, nígbà tí ìwọ bá sì pè wọ́n, wọn kì yóò dáhùn Nítorí náà, sọ fún wọn pé Èyí ni orílẹ̀ èdè tí kò gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ tàbí kí ó ṣe ìgbọ́ràn sí ìbáwí Ọ̀rọ̀ òtítọ́ kò sí ní ètè wọn ṣe irun yín kí ẹ sì dàanù, pohùnréré ẹkún lorí òkè aṣálẹ̀, nítorí Olúwa ti kọ ìran yìí tí ó wà lábẹ́ ìbínú rẹ̀ sílẹ̀  Àwọn ènìyàn Júdà ti ṣe búburú lójú mi, ni Olúwa wí Wọ́n ti to àwọn ère ìríra wọn jọ sí ilé tí a fi orúkọ mi pè wọ́n sì ti sọ ọ́ di àìmọ́ Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga ti Tófẹ́tì ní àfonífojì Beni Hínómí láti sun àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn nínú iná èyí tí èmi kò paláṣẹ tí kò sì wá sí ọkàn mi Nítorí náà kíyèsára ọjọ́-ń-bọ̀, ni Olúwa wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Táfétì tàbí àfonífojì ti Beni Hínómì àfonífojì ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tófẹ́tì títí kò fi ní sí àyè mọ́ Nígbà náà ni òkú àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀, kò sì ní sí ẹnìkan tí yóò dẹ́rùbà wọ́n Èmi yóò mú òpin bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú àti ohùn àwọn tọkọ tìyàwó ní àwọn ìlú Júdà àti ní ìgboro Jérúsálẹ́mù, nítorí tí ilẹ̀ náà yóò di ahoro Ẹ̀ṣẹ̀ Àti Ìjìyà  Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, wọn yóò mú egungun àwọn ọba Júdà àti egungun àwọn ijoye, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù kúrò nínú ibojì A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dà bí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀ Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí Wí fún wọn pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí  Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀ wọn kì í padà dìde bí Nígbà tí ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ, kì í yí padà bí È é ṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀ Kílódé tí Jérúsálẹ́mù fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn, wọ́n kọ̀ láti yípadà Mo ti fetí sílẹ̀ dáradára, wọn kò sọ ohun tí ó tọ́ Kò sí ẹnìkan tó ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀, kí ó wí pé, Kí ni mo ṣe Olúkúlùkù ń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé mọ àkókò ìsípòpadà wọn Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ ohun tí Ọlọ́run wọn fẹ́  Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, Àwa gbọ́n, nítorí a ní òfin Olúwa , nígbà tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn akọ̀wé ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n, a ó dà wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa Irú ọgbọ́n wo ló kù tí wọ́n ní Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹlòmíràn láti èyí tó kéré jù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọn ni èrè àjẹjù ń já lẹ́nu àwọn wòlíì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò jinlẹ̀ Àlàáfíà, àlàáfíà, ni wọ́n ń wí, nígbà tí kò sí àlàáfíà Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn kò ní ìtìjú rárá wọn kò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ti ṣe ń mí oru-ìtìjú Nítorí náà wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú, a ó sì fà wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá ń fi ìyà jẹ wọ́n, ni Olúwa wí  Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò ni Olúwa wí Kì yóò sí èṣo lórí igi àjàrà, kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀ Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò   È é ṣe tí a fi jòkó ní ibí yìí A kó ara wa jọ! Jẹ́ kí a sá lọ sí ìlú olódi kí o sì ṣègbé síbẹ̀ Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pinnu pé a ó ṣègbé Yóò sì fún wa ní omi onímájèlé láti mu, nítorí àwa ti sẹ̀ sí i Àwa ń retí àlàáfíà, kò sí ire kan tí ó wá ní ìgbà ìmúláradá bí kò ṣe ìpayà nìkan Ìró ìfọnmú ẹsin àwọn ọlọ̀tẹ̀ là ń gbọ́ láti Dánì yíyan àwọn akọ ẹsin mú gbogbo ilẹ̀ wárìrì Wọ́n wá láti pa ilẹ̀ náà run, gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀ Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárin yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn, yóò sì bù yín jẹ, ni Olúwa wí Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì nínú mi Fetí sí igbe àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ tó jìn Olúwa kò ha sí ní Síóní bí Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni È é ṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn, pẹ̀lú àwọn òrìṣà àjòjì tí wọn kò ní láárí Ìkóórè ti ré kọ́ja, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí ṣíbẹ̀, a kò gbà wá là Níwọ̀n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú, mo sọ̀fọ, ìrora sì mú mi káká Kò sí òjé olóòrùn dídùn ní Gílíádì bí Ṣé kò sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀ Kí ló dé tí kò fi sí ìwòsàn fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi Áà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé Èmi yóò sì sunkún tọ̀sán tòru nítorí pípa àwọn ènìyàn mi Áà! èmi ìbá ní ilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò ní ihà kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀ kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn nítorí gbogbo wọn jẹ́ pańṣágà àjọ aláìsòótọ́ ènìyàn ni wọ́n Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀ bí ọfà láti fi pa irọ́ kì í ṣe nípa òótọ́ ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn, wọn kò sì náání mi, ní Olúwa wí Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ nítorí pé oníkálukú arákùnrin jẹ́ atannijẹ, oníkálukú ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́ Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́ Kò sì sí ẹni tó sọ òótọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn láti máa purọ́ Wọ́n sọ ara wọn di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ Ó ń gbé ní àárin ẹ̀tàn wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú ẹ̀tàn wọn, ni Olúwa wí Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí Wò ó, èmi dán wọn wo nítorí pé kí ni èmi tún le è ṣe Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró ó ń sọ ẹ̀tàn oníkálukú sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládúgbò rẹ̀ ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀ Èmi kì yóò háa fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí ni Olúwa wí Èmi kì yóò ha gbẹ̀san ara mi lórí irú orílẹ̀ èdè yìí bí Èmi yóò sì sunkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkè àti ẹkún ìrora lórí pápá oko ihà wọ̀n-ọn-nì Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì kọjá ní ibẹ̀ A kò sì gbọ́ igbe ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti sá lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ Èmi yóò sì sọ Jérúsálẹ́mù di òkìtì àlàpà àti ìhò àwọn ìkokò Èmi ó sì sọ ìlú Júdà di ahoro tí ẹníkẹ́ní kò sì ní le è gbé Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀ È é ṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí ihà, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Báálì gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé Èmi yóò sì tú wọn ká láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀ Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí Ṣáà wò ó nísisìnyìí! Ké sí obìnrin ọlọ́fà nì kí ó wá sì ránsẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn Jẹ́ kí wọn wá kíákíá, kí wọn wá pohùnréré ẹkún lé wa lórí títí ojú wa yóò fi ṣàn fún omijé tí omi yóò sì máa ṣàn àwọn ìpéǹpéjú wa A gbọ́ igbe ìpohùnréré ẹkún ní Síónì Àwa ti ṣègbé tó! A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀, nítorí pé àwọn ilé wa ti parun   Nísínsìnyìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Sí etí yín sí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ Kọ́ àwọn ọmọbìnrin yín ní ìpohùnréré ẹkún, kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé ó sì ti wọ odi alágbára wa ó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní àdúgbò àti àwọn ọ̀dọ́mọ́kùnrin kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba Sọ pé, Èyí ni ohun tí Olúwa wí  Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubú bí ààtàn ní oko gbangba àti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórè láìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ   Èyí ni ohun tí Olúwa wí Má ṣe jẹ́ kí ọlọgbọ́n yangàn nítorí ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbára nítorí rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀ Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé òun ní òye, òun sì mọ̀mí wí pé, Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́ ìdájọ́ àti òdodo ní ayé nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí, Olúwa wí Ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan Éjíbítì, Júdà, Édómù, Ámónì, Móábù àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jínjìn réré ní ihà Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Ísírẹ́lì sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn Ọ̀rọ̀ Di Ènìyàn Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà Òun ni ó sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtètèkọ́ṣe Nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé, Ìmọ́lẹ̀ náà sì ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì borí rẹ̀ Ọkùnrin kan wà tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Jòhánù Òun ni a sì rán fún ẹ̀rí, kí ó lè ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo ènìyàn kí ó lè gbàgbọ́ nípaṣẹ̀ rẹ̀ Òun fúnrarẹ̀ kì í ṣe Ìmọ́lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n a rán an wá láti ṣe ẹlẹ́rìí fún Ìmọlẹ̀ náà Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń bẹ tí ń tan ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé Òun sì wà ní ayé, àti pé, nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ṣùgbọ́n ayé kò sì mọ̀ ọ́n Ó tọ àwọn tirẹ̀ wá, àwọn tirẹ̀ kò sì gbà á Ṣùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, àní àwọn náà tí ó gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́, àwọn ni ó fi agbára fún láti di ọmọ Ọlọ́run Àwọn ọmọ tí kì íṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo Òun ọmọ bíbí kan ṣoṣo, àní Àyànfẹ́ rẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ Jòhánù sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀ jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi   Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún Nítorí pé nípaṣẹ̀ Mósè ni a ti fi òfin fún ni oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ ti ipaṣẹ̀ Jésù Kírísítì wá Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọ́run rí, ṣùgbọ́n Òun, àní Àyànfẹ́ rẹ̀ kan ṣoṣo, tí ń bẹ ní oókan àyà Baba, Òun náà ni ó fi í hàn Èyí sì ni ẹ̀rí Jòhánù, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì láti Jérúsálẹ́mù wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe Òun kò sì kùnà láti jẹ́wọ́, ṣùgbọ́n òun jẹ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ pé, Èmi kì í ṣe Kírísítì náà Wọ́n sì bi í léèrè pé, Ta há ni ìwọ Èlíjà ni ìwọ bí Ó sì wí pé, Èmi kọ́, Ìwọ ni wòlíì náà bí Ó sì dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́ Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀ wọ́n wí fún un pé, Ta ni ìwọ í ṣe Fún wa ní ìdáhùn kí àwa kí ó lè mú èsì padà tọ àwọn tí ó rán wa wá lọ Kí ni ìwọ wí nípa ti ara rẹ Jòhánù sì fi ọ̀rọ̀ wòlíì Àìṣáyà fún wọn ní èsì pé, Èmi ni ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, Ẹ ṣe ọ̀nà Olúwa ní títọ́   Ọ̀kan nínú àwọn Farisí tí a rán bi í léèrè pé, Èéṣe tí ìwọ fí ń bamitíìsì nígbà náà, bí ìwọ kì í bá ṣe Kírísítì, tàbí Èlíjà, tàbí wòlíì náà Jòhánù dá wọn lóhùn, wí pé, Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ẹnìkan dúró láàárin yín, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀ Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Bétanì ní òdì kejì odò Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti ń ṣe ìtẹ̀bọmi Ní ọjọ́ kejì Jòhánù rí Jésù tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ! Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi pọ̀ jù mí lọ nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi Èmi gan-an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Ísírẹ́lì Nígbà náà ni Jòhánù jẹ́rìí sí i pé Mo rí Ẹ̀mi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e Èmí kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitíìsì sọ fún mi pé, Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run Ní ọjọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jòhánù dúró, pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Nígbà tí ó sì rí Jésù bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run! Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì gbọ́ ohun tí ó wí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì í tọ Jésù lẹ́yìn Nígbà náà ni Jésù yípadà, ó rí i pé wọ́n ń tọ Òun lẹ́yìn, ó sì béèrè pé, Kí ni ẹ̀yin ń wá Wọ́n wí fún un pé, Rábì , Níbo ni ìwọ ń gbé Ó wí fún wọn pé, Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́ Ańdérù, arákùnrin Símónì Pétérù, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jòhánù, tí ó sì tọ Jésù lẹ́yìn Ohun àkọ́kọ́ tí Ańdérù ṣe ni láti wá Símónì arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, Àwa ti rí Mèṣáyà Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jésù Jésù sì wò ó, ó wí pé, Ìwọ ni Símónì ọmọ Jónà Kéfà ni a ó sì máa pè ọ Ní ọjọ́ kéjì Jésù ń fẹ́ jáde lọ sí Gálílì, ó sì rí Fílípì, ó sì wí fún un pé, Má a tọ̀ mí lẹ́yìn Fílípì gẹ́gẹ́ bí i Ańdérù àti Pétérù, jẹ́ ará ìlú Bẹtiṣáídà Fílípì rí Nàtaníẹ́lì, ó sì wí fún un pé, Àwa ti rí ẹni náà tí Mósè kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀—Jésù ti Násárẹ́tì, ọmọ Jósẹ́fù Nàtaníẹ́lì béèrè pé, Násárẹ́tì Ohun rere kan há lè ti ibẹ̀ jáde Fílípì wí fún un pé, Wá wò ó Jésù rí Nàtaníẹ́lì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, Èyí ni ọmọ Ísírẹ́lì tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí Nàtaníẹ́lì béèrè pé, Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí Jésù sì dáhùn pé, Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Fílípì tó pè ọ́ Nígbà náà ni Nàtaníẹ́lì sọ ọ́ gbangba pé, Rábì, Ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run Ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì Jésù sì wí fún un pé, Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀ jù ìwọ̀nyí lọ Nígbà náà ni ó fi kún un pé, Èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹ̀yin yóò rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run yóò sì máa gòkè, wọ́n ó sì máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ Ènìyàn Agbo Kan Àti Olùṣọ́ Àgùntàn Kan Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí kò bá gba ẹnu ọ̀nà wọ inú agbo àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó bá gba ibòmíràn gun òkè, Òun náà ni olè àti ọlọ́sà Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ti ẹnu-ọ̀nà wọlé, Òun ni olùṣọ́ àwọn àgùntàn Òun ni osọ́nà yóò ṣílẹ̀kùn fún àwọn àgùntàn gbọ́ ohùn rẹ̀ ó sì pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ lórúkọ, ó sì se amọ̀nà wọn jáde Nígbà tí ó bá sì ti mú àwọn àgùntàn tirẹ̀ jáde, yóò ṣíwájú wọn, àwọn àgùntàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀ Wọn kò jẹ́ tọ àlejò lẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọn a sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ nítorí tí wọn kò mọ ohùn àlejò Òwe yìí ni Jésù pa fún wọn ṣùgbọ́n òye ohun tí nǹkan wọ̀nyí jẹ́ tí ó ń sọ fún wọn kò yé wọn Nítorí náà Jésù tún wí fún wọn pé, Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn Olè àti ọlọ́sà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ ti wọn Èmi ni ìlẹ̀kùn bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, Òun ni a ó gbà là, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀ Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn rere olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́ àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkokò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri Òun sá lọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn Èmi ni olùsọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn ó sì gbọ́ ohùn mi wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùsọ́-àgùntàn kan Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á Ẹnìkan kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀, mo sì lágbára láti tún gbà á Àṣẹ yìí ni mo ti gbà wá láti ọ̀dọ̀ Baba mi Nítorí náà ìyapa tún wà láàrin àwọn Júù nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wí pé, Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú èéṣe tí ẹ̀yin fi ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ Àwọn mìíràn wí pé, Ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù Ẹ̀mi èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí Ó sì jẹ́ àjọ̀dún ìyàsímímọ́ ní Jérúsálẹ́mù, ìgbà òtútù ni Jésù sì ń rìn ní tẹ́mpílì, ní ìloro Sólómónì, Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó Bí ìwọ bá ni Kírísítì náà, wí fún wa gbangba Jésù dá wọn lóhùn pé, Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́ iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín Àwọn àgùntàn mi ń gbọ́ ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ kò sì sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi Ọ̀kan ni èmi àti Baba mi Àwọn Júù sì tún he òkúta, láti sọ lù ú Jésù dá wọn lóhùn pé, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fi hàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá nítorí èwo nínú iṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe sọ mí ní òkúta Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, Àwa kò sọ ọ́ lókúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-ọ̀dì àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ ṣe Ọlọ́run Jésù dá wọn lóhùn pé, A kò ha tí kọ ọ́ nínú òfin yín pé, Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́ Bí ó bá pè wọ́n ní Ọlọ́run, àwọn ẹni tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, a kò sì lè ba ìwé-mímọ́ jẹ́, Ẹ̀yin ha ń wí ní ti ẹni tí Baba yà sí mímọ́, tí ó sì rán sí ayé pé Ìwọ ń sọ̀rọ̀ òdì, nítorí tí mo wí pé, Ọmọ Ọlọ́run ni mí Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́ Ṣùgbọ́n bí èmi bá ṣe wọ́n, bí ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gbà iṣẹ́ náà gbọ́ kí ẹ̀yin baà lè mọ̀, kí ó sì lè yé yín pé, Baba wà nínú mi, èmi sì wà nínú rẹ̀ Wọ́n sì tún ń wá ọ̀nà láti mú un ó sì bọ́ lọ́wọ́ wọn Ó sì tún kọjá lọ sí apá kéjì Jodánì sí ibi tí Jòhánù ti kọ́kọ́ ń bamítísì níbẹ̀ ni ó sì jókòó Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, Jòhánù kò ṣe iṣẹ́ àmì kan Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Jòhánù sọ nípa ti ọkùnrin yìí Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbàágbọ́ Ikú Lásárù Ara ọkùnrin kan sì ṣe aláìdá, Lásárù, ará Bẹ́tẹ́nì, tí í ṣe ìlú Màríà àti Màta arábìnrin rẹ̀ Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ ránsẹ́ sí i, wí pé, Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá Nígbà tí Jésù sì gbọ́, ó wí pé, Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún Ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀ Jésù sì fẹ́ràn Màta, àti arábìnrin rẹ̀ àti lásárù Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Jùdíà Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, Rábì, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀ Jésù dáhùn pé, Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀ Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, Lásárù ọ̀rẹ́ wa sùn ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀ Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, Olúwa, bí ó bá se pé ó sùn, yóò sàn Ṣùgbọ́n Jésù ń sọ ti ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn gbangba pé, Lásárù kú, Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀, Kí ẹ le gbàgbọ́ ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ Nítorí náà Tómásì, ẹni tí à ń pè ní Dídímù, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú Nítorí náà nígbà tí Jésù dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ijọ́ mẹ́rin ná, Ǹjẹ́ Bétanì sún mọ́ Jérúsálẹ́mù tó ibùsọ Mẹ́ẹ̀dógún Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Màta àti Màríà láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn Nítorí náà, nígbà tí Màta gbọ́ pé Jésù ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀ ṣùgbọ́n Màríà jòkó nínú ilé Nígbà náà, ni Màta wí fún Jésù pé, Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ Jésù wí fún un pé, Arákùnrin rẹ yóò jíǹde Màta wí fún un pé, Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn Jésù wí fún un pé, Èmi ni àjíǹde àti ìyè ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láàyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́ Ó wí fún un pé, Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kírísítì náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Màríà arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́ Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ Jésù kò tíì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Màrta ti pàdé rẹ̀ Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Màríà tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀ Nígbà tí Màríà sì dé ibi tí Jésù wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, Olúwa, ìbáṣe pé ìwọ ti wà níhín-ín, arákùnrin mi kì bá kú Nígbà tí Jésù rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ Ó sì wí pé, Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí Wọ́n sì wí fún un pé, Olúwa, wá wò ó Jésù sọkún Nítorí náà àwọn Júù wí pé, Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó! Àwọn kan nínú wọn sì wí pé, Ọkùnrin yìí, ẹni tí ó la ojú afọ́jú, kò lè ṣeé kí ọkùnrin yìí má kú bí Nígbà náà ni Jésù tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀ Jésù wí pé, Ẹ gbé òkúta náà kúrò! Màtá, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí nítorí pé ó di ijọ́ kẹrin tí ó tí kú Jésù wí fún un pé, Èmi kò ti wí fún ọ pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́, ìwọ ó rí ògo Ọlọ́run Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò Jésù sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn baà lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, Lásárù, jáde wá Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú Jésù wí fún wọn pé, Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó má a lọ! Nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ó wá sọ́dọ̀ Màríà, tí wọ́n rí ohun tí Jésù ṣe, ṣe gbà á gbọ́ Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn tọ àwọn Farisí lọ, wọ́n sì sọ fún wọn ohun tí Jésù ṣe Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí pe ìgbìmọ̀ jọ, wọ́n sì wí pé, Kínni àwa ń ṣe Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì Bí àwa bá fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yóò gbà á gbọ́ àwọn ará Rómù yóò sì wá gba ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè wa pẹ̀lú Ṣùgbọ́n Káyáfà, ọ̀kan nínú wọn, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó wí fún wọn pé, Ẹ̀yin kò mọ ohunkóhun rárá! Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ronú pé, ó sàǹfàní fún wa, kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn kí gbogbo orílẹ̀-èdè má baà ṣègbé Kì í ṣe fún ara rẹ̀ ni ó sọ èyí ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jésù yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà Kì sì í ṣe kìkì fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jésù yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á Nítorí náà Jésù kò rìn ní gbangba láàárin àwọn Júù mọ́ ṣùgbọ́n ó ti ibẹ̀ lọ sí ìgbéríko kan tí ó sún mọ́ ihà, sí ìlú ńlá kan tí a ń pè ní Éfúráímù, níbẹ̀ ni ó sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì sún mọ́ etílé ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ìgbéríko sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù ṣáájú ìrékọjá, láti ya ara wọn sí mímọ́ Nígbà náà ni wọ́n ń wá Jésù, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ̀, bí wọ́n ti dúró ní tẹ́mpílì, wí pé, Ẹ̀yin ti rò ó sí Pé kì yóò wá sí àjọ Ǹjẹ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí ti pàṣẹ pé bí ẹnìkan bá mọ ibi tí ó gbé wà, kí ó fi í hàn, kí wọn baà lè mú un Ìfàmì-Òróró Yàn Jésù Ni Bẹ́tanì Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ìjọ́ mẹ́fà, Jésù wá sí Bẹ́tanì, níbi tí Lásárù wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jésù jí dìde kúrò nínú òkú Wọ́n sì se àṣè alẹ́ fún un níbẹ̀ Màtá sì ń ṣe ìránṣẹ́ ṣùgbọ́n Lásárù Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀ Nígbà náà, Màtá mú òróró ìkunra nádì, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jésù ní ẹṣẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹṣẹ̀ rẹ̀ nù ilẹ̀ sì kún fún òórùn ìkunra náà Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Júdásì Isíkáríótù, ọmọ Símónì ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, Èé ṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn talákà Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn talákà ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó sì ní àpò, a sì máa gbé ohun tí a fi sínú rẹ̀ Nígbà náà ni Jésù wí pé, Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin sáà ní talákà pẹ̀lú yín ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo Nítorí náà, ìjọ ènìyàn nínú àwọn Júù ni ó mọ̀ pé ó wà níbẹ̀ wọ́n sì wá, kì í ṣe nítorí Jésù nìkan, ṣùgbọ́n kí wọn lè rí Lásárù pẹ̀lú, ẹni tí ó ti jí dìde kúrò nínú òkú Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lásárù pẹ̀lú Nítòrí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jésù gbọ́ Ní ijọ kejì nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wá sí àjọ gbọ́ pé, Jésù ń bọ̀ wá sí Jérúsálẹ́mù Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé, Hòsánnà! Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀wá ní orúkọ Olúwa, ọba Ísríẹ́lì! Nígbà tí Jésù sì rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ógùn ún gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé pé, Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Síónì Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá, Ó jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́ktẹ́ Nǹkan wọ̀nyí kò tètè yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jésù lógo, nígbà náà ni wọ́n rántí pé, a kọ̀wé ǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ sí i Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Lásárù jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rí sí i Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí Nítorí náà àwọn Farisí wí fún ara wọn pé, Ẹ kíyèsi bí ẹ kò ti lè borí ní ohunkóhun Ẹ wo bí gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́! Àwọn Gíríkì kan sì wà nínú àwọn tí ó gòkè wá láti sìn nígbà àjọ Àwọn wọ̀nyí ni ó tọ Fílípì wá, ẹni tí í ṣe ará Bẹtisáídà tí Gálílì, wọ́n sì ń bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, Alàgbà, àwa ń fẹ́ rí Jésù! Fílípì wá, ó sì sọ fún Ańdérù Ańdérù àti Fílípì wá, wọ́n sì sọ fún Jésù Jésù sì dá wọn lóhùn pé, Wákàtí náà dé, tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé àlìkámà bá bọ́ sí ilẹ̀, tí ó bá sì kú, ó wà ní òun nìkan ṣùgbọ́n bí ó bá kú, a sì so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn àti níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún Ní ìsinsin yìí ni a ń pọ́n ọkàn mi lójú kínni èmi ó sì wí Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí Rárá, ṣùgbọ́n nítorí èyì ni mo ṣe wá sí wákàtí yìí Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo! Nígbà náà ni ohùn kan ti ọ̀run wá, wí pé, Èmi ti ṣe é lógo! Nítorí náà ìjọ ènìyàn tí ó dúró níbẹ̀, tí wọ́n sì gbọ́ ọ, wí pé, àrá ń sán àwọn ẹlòmíràn wí pé, Ańgẹ́lì kan ni ó ń bá a sọ̀rọ̀ Jésù sì dáhùn wí pé, Kì í ṣe nítorí mi ni ohùn yìí ṣe wá, bí kò ṣe nítorí yín Ní ìsinsin yìí ni ìdájọ́ ayé yìí dé nísinsin yìí ni a ó lé aládé ayé yìí jáde Àti èmi, bí a bá gbé mi sókè èmi ó fa gbogbo ènìyàn sọ́dọ̀ ara mi! Ṣùgbọ́n ó wí èyí, ó ń ṣàpẹrẹ irú ikú tí òun ó kú Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kírísítì wà títí láéláé ìwọ ha ṣe wí pé, A ó gbé ọmọ ènìyàn sókè Ta ni ó ń jẹ́ ọmọ ènìyàn yìí Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, Nígbà díẹ̀ sí i ni ìmọ́lẹ̀ wà láàárin yín, ẹ máa rìn nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má ṣe bá yín ẹni tí ó bá sì ń rìn ní òkùnkùn kò mọ ibi òun gbé ń lọ Nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀! Nǹkan wọ̀nyí ni Jésù sọ, ó sì jáde lọ, ó fi ara pamọ́ fún wọn Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́ Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Ìsàíàh lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé Olúwa, tani ó gba ìwàásù wa gbọ́ Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Ìsáyà sì tún sọ pé Ó ti fọ́ wọn lójú, Ó sì ti sé àyà wọn le Kí wọn má baà fi ojú wọn rí, Kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, Kí wọn má baà yípadà, kí wọn má baà mú wọn láradá Nǹkan wọ̀nyí ni Ìsáyà wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisí wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sínágọ́gù Nítorí wọ́n fẹ́ ìyìn ènìyàn ju ìyìn ti Ọlọ́run lọ Jésù sì kígbe ó sì wí pé, Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, èmi kọ́ ni ó gbàgbọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó rán mi Ẹni tí ó bá sì rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó wá sí ayé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ má ṣe wà nínú òkùnkùn Bí ẹnikẹ́ni bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa wọ́n mọ́, èmi kì yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí tí èmi kò wá láti ṣe ìdájọ́ ayé, bí kò ṣe láti gba ayé là Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹ́yìn Nítorí èmi kò dá ọ̀rọ̀ sọ fún ara mi, ṣùgbọ́n Baba tí ó rán mi, òun ni ó ti fún mi ní àṣẹ, ohun tí èmi ó sọ, àti èyí tí èmi ó wí Èmi sì mọ̀ pé ìyè àìnípẹ̀kun ni òfin rẹ̀ nítorí náà, àwọn ohun tí mo bá wí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wí! Jésù Wẹ Ẹsẹ̀ Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Rẹ̀ Ǹjẹ́ kí àjọ ìrékọjá tó dé, nígbà tí Jésù mọ̀ pé, wákàtí rẹ̀ dé tan, tí òun ó ti ayé yìí kúrò lọ sọ́dọ̀ Baba, fífẹ́ tí ó fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Júdásì Isíkáríótù ọmọ Símónì láti fi í hàn Tí Jésù sì ti mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, àti pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, òun sì ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run Ó dìde ní ìdí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi agbádá rẹ̀ lélẹ̀ ní apákan nígbà tí ó sì mú asọ ìnura, ó di ara rẹ̀ ní àmùrè Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú àwòkòtò kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í máa wẹ ẹṣẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń fi aṣọ ìnura tí ó fi di àmùrè nù wọ́n Nígbà náà ni ó dé ọ̀dọ̀ Símónì Pétérù, òun sì wí fún un pé, Olúwa, ìwọ yóò ha wẹ ẹsẹ̀ mi Jésù dá a lóhùn, ó sì wí fún un pé, Ohun tí èmi ń ṣe ni ìwọ kò mọ̀ nísinsin yìí ṣùgbọ́n yóò yé ọ ní ìkẹyìn Pétérù wí fún un pé, Ìwọ kì yóò wẹ̀ mí ní ẹṣẹ̀ Jésù sì da lóhùn pé, Bí èmi kò bá wẹ̀ ọ́, ìwọ kò ní ìpín ní ọ̀dọ̀ mi Símónì Pétérù wí fún ún pé, Olúwa, kì í ṣe ẹṣẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n àti ọwọ́ àti orí mi pẹ̀lú Jésù wí fún un pé, Ẹni tí a wẹ̀ kò tún fẹ́ ju kí a san ẹṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mọ́ níbi gbogbo ẹ̀yin sì mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo yín Nítorí tí ó mọ ẹni tí yóò fi òun hàn nítorí náà ni ó se wí pé, Kìí ṣe gbogbo yín ni ó mọ́ Nítorí náà lẹ́yìn tí ó wẹ ẹṣẹ̀ wọn tán, tí ó sì ti mú agbádá rẹ̀, tí ó tún jókòó, ó wí fún wọn pé, Ẹ̀yin mọ ohun tí mo ṣe sí yín bí Ẹ̀yin ń pè mí ní Olùkọ́ àti Olúwa ẹ̀yin wí rere bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́ Ǹjẹ́ bí èmi tí í ṣe Olúwa àti Olùkọ́ yín bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó tọ́ kí ẹ̀yin pẹ̀lú sì máa wẹ ẹṣẹ̀ ara yín Nítorí mo fi àpẹẹrẹ fún yín, kí ẹ̀yin lè máa ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí yín Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ-ọ̀dọ̀ kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí a rán kò tóbi ju ẹni tí ó rán an lọ Bí ẹ̀yin bá mọ nǹkan wọ̀nyí, alábùkún fún ni yín, bí ẹ̀yin bá ń se wọ́n! Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ èmi mọ àwọn tí mo yàn ṣùgbọ́n kí ìwé-mímọ́ bá à lè ṣẹ, Ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi Láti ìsinsìn yìí lọ ni mo wí fún un yín kí ó tó dé, pé nígbà tí ó bá dé, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé èmi ni Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, Ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán, ó gbà mí Ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi Nígbà tí Jésù ti wí nǹkan wọ̀nyí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú nínú rẹ̀, ó sì jẹ́rìí, ó sì wí pé, Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, ọ̀kan nínú yín yóò dà mí Àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ ń wò ara wọn lójú, wọ́n ń siyè méjì ti ẹni tí ó wí Ǹjẹ́ ẹnìkan rọ̀gbọ̀kú sí àyà Jésù, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí Jésù fẹ́ràn Nítorí náà ni Símónì Pétérù sàpẹrẹ sí i, ó sì wí fún un pé, Wí fún wa ti ẹni tí o ń sọ Ẹni tí ó sún mọ àya rẹ̀ bí i léèrè wí pé, Olúwa, taa ni í se Nítorí náà Jésù dáhùn pé, Òun náà ni, ẹni tí mo bá fi àkàrà fún nígbà tí mo bá fi run àwo Nígbà tí ó sì fi run ún tan, ó fi fún Júdásì Ísíkárótù ọmọ Símónì Ní kété tí Júdásì gba àkàrà náà ni Sátanì wọ inú rẹ̀ lọ Nítorí náà Jésù wí fún un pé, Ohun tí ìwọ ń se nì, yára ṣe é kánkán Kò sì sí ẹnìkan níbi tábìlì tí ó mọ ìdí tí ó ṣe sọ èyí fún un Nítorí àwọn mìíràn nínú wọn rò pé, nitorí Júdásì ni ó ni àpò, ni Jésù fi wí fún un pé, Ra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kò le ṣe aláìní fún àjọ náà tàbí kí ó lè fi nǹkan fún àwọn talákà Nígbà tí ó sì ti gbà òkèlè náà tan, ó jáde lójúkan náà òru sì ni Nítorí náà nígbà tí ó jáde lọ tan, Jésù wí pé, Nísinsìn yìí ni a yin ọmọ-ènìyàn lógo, a sì yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀ Bí a bá yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀, Ọlọ́run yóò sì yìn ín lógo nínú òun tìkára rẹ̀, yóò sì yìn ín lógo nísinsìn yìí Ẹ̀yin ọmọ mi, nígbà díẹ̀ sí i ni èmi wà pẹ̀lú yín Ẹ̀yin ó wá mi àti gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún àwọn Júù pé, Níbití èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì ó le wà bẹ́ẹ̀ ni mo sì wí fún yín nísìnsìn yìí Òfin titun kan ni mo fi fún yín, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ ọmọnìkejì yín gẹ́gẹ́ bí èmi ti fẹ́ràn yín, kí ẹ̀yin kí ó sì lè fẹ́ràn ọmọnìkejì yín Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin ń se, nígbà tí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ sí ọmọ ẹnìkejì yín Símónì Pétérù wí fún un pé, Olúwa, níbo ni ìwọ ń lọ Jésù dá a lóhùn pé, Níbi tí èmi ń lọ, ìwọ kì yóò lè tọ̀ mí nísinsin yìí ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ̀ mí níkẹyìn Pétérù wí fún un pé, Olúwa èése tí èmi kò fi le tọ̀ ọ́ nísinsìn yìí Èmi ó fi ẹ̀mi mi lélẹ̀ nítorí rẹ Jésù da lóhùn wí pé, Ìwọ ó ha fi ẹ̀mí rẹ lélẹ̀ nítorí mi Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, àkùkọ kì yóò kọ, kí ìwọ kí ó tó ṣẹ́ mi nígbà mẹ́ta! Jésù Sọ̀rọ̀ Ìtùnú Fún Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Rẹ̀ Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú ẹ gba Ọlọ́run gbọ́, kí ẹ sì gbà mí gbọ́ pẹ̀lú Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé ni ó wà ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ìbá tí sọ fún yín Èmi ń lọ láti pèṣè àyè sílẹ̀ fún yín Bí mo bá sì lọ láti pèṣè àyè sílẹ̀ fún un yín, èmi ó tún padà wá, èmi ó sì mú yín lọ sọ́dọ̀ èmi tìkáara mi pé níbi tí èmi gbé wà, kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ pẹ̀lú Ẹ̀yin mọ ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ sì mọ ọ̀nà náà Tómásì wí fún un pé, Olúwa, a kò mọ ibi tí ìwọ ń lọ, a ó ha ti ṣe mọ ọ̀nà náà Jésù dá wọn lóhùn pé, Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípaṣẹ̀ mi Ìbáṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú láti ìsinsinyìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i Fílípì wí fún un pé, Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa Jésù wí fún un pé, Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ fílípì Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba Ìwọ ha ti ṣe wí pé, Fi Baba hàn wá! Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, Èmi wà nínu Baba, àti pé Baba wà nínú mi Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ ṣùgbọ́n Baba ti wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ Ẹ gbà mí gbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, Baba sì wà nínú mi bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí àwọn iṣẹ́ náà pàápàá! Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, oun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ Bí ẹ̀yin bá bèèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi ó ṣe é Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́ Nígbà náà èmi yóò wá bèèrè lọ́wọ́ Baba Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé Òun ni Ẹ̀mí Mímọ́ òtítọ́ Ayé kò le gbà á Ṣé ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí Òun náà ti wà pẹ̀lú yín Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀ Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìní Òlùtùnú, kí ẹ wá dàbí ọmọ tí kò ní òbí Rárá o! Mo tún ń tọ̀ yín bọ̀ Nígbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò rí mi mọ́ ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò rí mi nítorí tí èmi wà láàyè, ẹ̀yin ó wà láàyè pẹ̀lú Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì ń pa wọ́n mọ́, òun ni ẹni tí ó fẹ́ràn mi ẹni tí ó bá sì fẹ́ràn mi, a ó fẹ́ràn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba mi, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un Júdásì wí fún un pé, Olúwa, èé ha ti ṣe tí ìwọ ó fi ara rẹ hàn fún àwa, tí kì yóò sì ṣe fún aráye Jésù dáhùn ó sì wí fún un pé, Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́ Baba mi yóò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀ Ẹni tí kò fẹ́ràn mi ni kò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́ ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin ń gbọ́ kì í ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ti Baba tí ó rán mi Nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fún yín, nígbà tí mo ń bá yín gbé Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, Èmi ń lọ, èmi fi fún yín Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì Ẹ̀yin sá ti gbọ́ bí mo ti wí fún yín pé, Èmi ń lọ, èmi ó sì tọ̀ yín wá Ìbáṣe pé ẹ̀yin fẹ́ràn mi, ẹ̀yin ìbá yọ̀ nítorí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba nítorí Baba mi tóbi jù mí lọ Èmi sì ti sọ fún yín nísinsìn yìí kí ó tó ṣẹ, pé nígbà tí ó bá ṣẹ, kí ẹ lè gbàgbọ́ Èmi kì ó bá yín sọ̀rọ̀ púpọ nítorí aláde ayé yí wá, kò sì ní nǹkankan lọ́dọ̀ mi Ṣùgbọ́n nítorí kí ayé lè mọ̀ pé èmi fẹ́ràn Baba gẹ́gẹ́ bí Baba sì ti fi àṣẹ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi ń ṣe Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a lọ kúrò níhínyìí Àjàrà Àti Ẹ̀ka Rẹ̀ Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni Olùtọ́gbàse Gbogbo ẹ̀ka nínú mi tí kò bá so èso, òun a mú kúrò gbogbo ẹ̀ka tí ó bá sì so èṣo, òun a wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí ó lè so èso sí i Ẹ̀yin mọ́ nísinsin yìí nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín Ẹ máa gbé inú mi, èmi ó sì máa gbé inú yín Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ bí kò ṣe pé ó ba ń gbé inú àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ bá ń gbé inú mi Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka Ẹni tí ó ń gbé inú mi, àti èmi nínú rẹ̀, òun ni yóò so èṣo ọ̀pọ̀lọpọ̀ nítorí ní yíyara yín kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ kò lè ṣe ohun kan Bí ẹnìkan kò bá gbé inú mi, a gbé e sọnù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka, a sì gbẹ wọn a sì kó wọn jọ, wọn a sì sọ wọ́n sínú iná, wọn a sì jóná Bí ẹ̀yin bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi bá sì gbé inú yín, ẹ ó bèèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, a ó sì ṣe é fún yín Nínú èyí ní a yìn Baba mi lógo pé, kí ẹ̀yin kí ó máa so èṣo púpọ̀ ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì fẹ́ yín ẹ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀ Bí ẹ̀yin bá pa òfin mi mọ́, ẹ ó dúró nínú ìfẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀ Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí ayọ̀ mi kí ó lè wà nínú yín, àti kí ayọ̀ yín kí ó lè kún Èyí ni òfin mi, pé kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín Kò sí ẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ Ọ̀rẹ́ mi ni ẹ̀yin ń ṣe, bí ẹ bá ṣe ohun tí èmi pàṣẹ fún yín Èmi kò pè yín ní ọmọ ọ̀dọ̀ mọ́ nítorí ọmọ ọ̀dọ̀ kò mọ ohun tí olúwa rẹ̀ ń ṣe ṣùgbọ́n èmi pè yín ní ọ̀rẹ́ nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, mo ti fi hàn fún yín Kì í ṣe ẹ̀yin ni ó yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni ó yàn yín, mo sì fi yín sípò, kí ẹ̀yin kí ó lè lọ, kí ẹ sì so èso, àti kí èṣo yín lè dúró kí ohunkóhun tí ẹ bá bèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, kí ó lè fi í fún yín Nǹkan wọ̀nyí ni mo paláṣẹ fún yín pé, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín Bí ayé bá kóríra yín, ẹ mọ̀ pé, ó ti kóríra mi ṣáájú yín Ìbáṣepé ẹ̀yin ń ṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ àwọn tirẹ̀ ṣùgbọ́n nítorí tí ẹ̀yin kì ń ṣe ti ayé, ṣùgbọ́n èmi ti yàn yín kúrò nínú ayé, nítorí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín Ẹ rántí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín pé, Ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju olúwa rẹ̀ lọ Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n ó sì pa ti yín mọ́ pẹ̀lú Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó ṣe sí yín, nítorí orúkọ mi, nítorí tí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi Ìbá ṣe pé èmi kò ti wá kí n sì ti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n di aláìríwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn Ẹni tí ó bá kórìíra mi, ó kórìíra Baba mi pẹ̀lú Ìbá ṣe pé èmi kò ti ṣe iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì láàárin wọn tí ẹlòmíràn kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n sì rí, wọ́n sì kórìíra àti èmi àti Baba mi Ṣùgbọ́n èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ nínú òfin wọn kí ó lè ṣẹ pé, Wọ́n kórìíra mi ní àìnídìí Ṣùgbọ́n nígbà tí Olùtùnú náà bá dé, ẹni tí èmi ó rán sí yín láti ọ̀dọ̀ Baba wá, àní Ẹ̀mí òtítọ́ nì, tí ń ti ọ̀dọ̀ Baba wá, òun náà ni yóò jẹ́rìí mi Ẹ̀yin pẹ̀lú yóò sì jẹ́rí mi, nítorí tí ẹ̀yin ti wà pẹ̀lú mi láti ìpìlẹ̀ṣẹ̀ wá Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí a má baà mú yín kọsẹ̀ Wọ́n ó yọ yín kúrò nínú Sínágógù àní, àkókò ń bọ̀, tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa yín, yóò rò pé òun ń ṣe ìsìn fún Ọlọ́run Nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó sì ṣe, nítorí tí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí Ṣùgbọ́n nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, pé nígbà tí wákàtí wọn bá dé, kí ẹ lè rántí wọn pé mo ti wí fún yín Ṣùgbọ́n èmi kò sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá, nítorí tí mo wà pẹ̀lú yín Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí èmi ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi kò sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó bi mí lérè pé, Níbo ni ìwọ ń lọ Ṣùgbọ́n nítorí mo sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín, ìbìnújẹ́ kún ọkàn yín Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ńsọ fún yín àǹfàní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráíyé níti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti níti ìdájọ́ Ní ti ẹ̀ṣẹ, nítorí tí wọn kò gbà mí gbọ́ Ní ti òdodo, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ̀yin kò sì mọ̀ mí Ní ti ìdájọ́, nítorí tí a ti ṣe ìdájọ́ aládé ayé yìí Mo ní ohun pípọ̀ láti sọ fún yín pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n nísinsìn yìí Ṣùgbọ́n nígbà tí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ náà bá dé, yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo nítorí kì yóò sọ ti ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, òun ni yóò máa sọ yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín Òun ó máa yìn mí lógo nítorí tí yóò gbà nínú ti èmi, yóò sì máa sọ ọ́ fún yín Ohun gbogbo tí Baba ní tèmi ni nítorí èyí ni mo ṣe wí pé, òun ó gba nínú tèmi, yóò sì sọ ọ́ fún yín Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba Nítorí náà òmíràn nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá ara wọn sọ pé, Kí ni èyí tí o wí fún wa yìí, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin kì yóò rí mi àti, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba Nítorí náà wọ́n wí pé, kí ni èyí tí ó wí yí, nígbà díẹ̀ Àwa kò mọ̀ ohun tí ó wí Jésù sáà ti mọ̀ pé, wọ́n ń fẹ́ láti bi òun léèrè, ó sì wí fún wọn pé, ẹ̀yin ń bi ara yín léèrè ní ti èyí tí mo wí pé, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ẹ̀yin ó máa sọkún ẹ ó sì máa pohùnréré ẹkún, ṣùgbọ́n àwọn aráyé yóò máa yọ̀ inú yín yóò sì di ayọ̀ Nígbà tí obìnrin bá ń rọbí, a ní ìbìnújẹ́, nítorí tí wákàtí rẹ̀ dé ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ti rí ọmọ náà tán, òun kì í sì í rántí ìrora náà mọ́, fún ayọ̀ nítorí a bí ènìyàn sí ayé Nítorí náà ẹ̀yin ní ìbànújẹ́ nísinsìn yìí ṣùgbọ́n èmi ó tún rí yín, ọkàn yín yóò sì yọ̀, kò sì sí ẹni tí yóò gba ayọ̀ yín lọ́wọ́ yín Àti ní ijọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá bèèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín Títí di ìsinyìí ẹ kò tíì bèèrè ohunkóhun ní orúkọ mi ẹ bèèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ ti Baba fún yín gbangba Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó bèèrè lọ́wọ́ Baba fún yín Nítorí tí Baba tìkara rẹ̀ fẹ́ràn yín, nítorí tí ẹ̀yin ti fẹ́ràn mi, ẹ sì ti gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni èmi ti jáde wá Mo ti ọ̀dọ̀ Baba jáde wá, mo sì wá sí ayé ẹ̀wẹ̀, mo fi ayé sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ Baba Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, Wò ó, nígbà yìí ni ìwọ ń sọ̀rọ̀ gbangba, ìwọ kò sì sọ ohunkóhun ní òwe Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé, ìwọ mọ̀ ohun gbogbo, ìwọ kò ní kí a bi ọ́ léèrè nípa èyí ni àwa gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ ti jáde wá Jésù dá wọn lóhùn pé, Ẹ̀yin gbàgbọ́ wàyí Kíyèsí i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀ ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀ ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú ṣùgbọ́n ẹ tújúká mo ti ṣẹ́gun ayé Jésù Gbàdúrà Fún Ara Rẹ̀ Nǹkan wọ̀nyí ni Jésù sọ, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ó sì wí pé Baba, wákàtí náà dé, yin ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ kí ó lè yìn ọ́ lógo pẹ̀lú Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fún un ní àṣẹ lórí ènìyàn gbogbo, kí ó lè fi ìyè àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó fi fún un Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jésù Kírísítì, ẹni tí ìwọ rán Èmi ti yìn ọ́ lógo ní ayé èmi ti parí iṣẹ́ tí ìwọ fi fún mi láti ṣe Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, Baba, ṣe mí lógo pẹ̀lú ara rẹ, ògo tí mo ti ní pẹ̀lú rẹ kí ayé kí ó tó wà Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fún mi láti inú ayé wá tìrẹ ni wọ́n ti jẹ́ rí, ìwọ sì ti fi wọ́n fún mi wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ Nísinsìn yìí, wọ́n mọ̀ pé ohunkóhun gbogbo tí ìwọ ti fi fún mi, láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni Nítorí ọ̀rọ̀ tí ìwọ fi fún mi, èmi ti fi fún wọn, wọ́n sì ti gbà á, wọ́n sì ti mọ̀ nítòótọ́ pé, lọ́dọ̀ rẹ ni mo ti jáde wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi Èmi ń gbàdúrà fún wọn èmi kò gbàdúrà fún aráyé, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ìwọ ti fi fún mi nítorí pé tìrẹ ni wọ́n íṣe Tìrẹ sáà ni gbogbo ohun tí í ṣe tèmi, àti tèmi sì ni gbogbo ohun tí í ṣe tìrẹ, a sì ti ṣe mí lógo nínú wọn Èmi kò sì sí ní ayé mọ́, àwọn wọ̀nyí sì ń bẹ ní ayé, èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ Baba mímọ́, pa àwọn tí o ti fifún mi mọ́, ní orúkọ rẹ, kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, àní gẹ́gẹ́ bí àwa Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn ní ayé, mo pa wọ́n mọ́ ní orúkọ rẹ àwọn tí ìwọ fifún mi, ni mo ti pamọ́, ẹnìkan nínú wọn kò sọnù bí kò ṣe ọmọ ègbé kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, nǹkan wọ̀nyí ni mo sì ń sọ ní ayé, kí wọn kí ó lè ní ayọ̀ mi ní kíkún nínú àwọn tìkára wọn Èmi ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn ayé sì ti kórìíra wọn, nítorí tí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé Èmi kò gbàdúrà pé, kí ìwọ kí ó mú wọn kúrò ní ayé, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ibi Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé Sọ wọ́n di mímọ́ nínú òtítọ́ òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rán mi wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán wọn sí ayé pẹ̀lú Èmi sì ya ara mi sí mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn tìkára wọn pẹ̀lú di mímọ́ nínú òtítọ́ Kì sì í ṣe kìkì àwọn wọ̀nyí ni mo ń gbàdúrà fún, ṣùgbọ́n fún àwọn pẹ̀lú tí yóò gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn Kí gbogbo wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti jẹ́ nínú mi, àti èmi nínú rẹ, kí àwọn pẹ̀lú kí ó lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa kí ayé kí ó lè gbàgbọ́ pé, ìwọ ni ó rán mi Ògo tí ìwọ ti fi fún mi ni èmi sì ti fi fún wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan Èmi nínú wọn, àti ìwọ nínú mi, kí a lè ṣe wọ́n pé ní ọ̀kan kí ayé kí ó lè mọ̀ pé, ìwọ ni ó rán mi, àti pé ìwọ sì fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́ràn mi Baba, èmi fẹ́ kí àwọn tí ìwọ fi fún mi, kí ó wà lọ́dọ̀ mi, níbi tí èmi gbé wà kí wọn lè máa wo ògo mi, tí ìwọ ti fi fún mi nítorí ìwọ sáà fẹ́ràn mi ṣíwájú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé Baba olódodo, ayé kò mọ̀ ọ́ ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́, àwọn wọ̀nyí sì mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi Mo ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn, èmi ó sì sọ ọ́ di mímọ̀ kí ìfẹ́ tí ìwọ fẹ́ràn mi, lè máa wà nínú wọn, àti èmi nínú wọn Wọ́n Mú Jésù Nígbà tí Jésù sì ti sọ nǹkan wọ̀nyí tán, ó jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sókè odò Kédírónì, níbi tí àgbàlá kan wà, nínú èyí tí ó wọ̀, Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Júdásì, ẹni tí ó dà á, sì mọ ibẹ̀ pẹ̀lú nítorí nígbà púpọ̀ ni Jésù máa ń lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Nígbà náà ni Júdásì, lẹ́yìn tí ó ti gba ẹgbẹ́ ọmọ ogun, àti àwọn oníṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí wá síbẹ̀ ti àwọn ti fìtílà àti ògùṣọ̀, àti ohun ìjà Nítorí náà bí Jésù ti mọ ohun gbogbo tí ń bọ̀ wá bá òun, ó jáde lọ, ó sì wí fún wọn pé, Ta ni ẹ ń wá Wọ́n sì dá a lóhùn wí pé, Jésù ti Násárétì Jésù sì wí fún wọn pé, Èmi nìyí Nítorí náà bí ó ti wí fún wọn pé, Èmi nìyí, wọ́n bì sẹ́yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀ Nítorí náà ó tún bi wọ́n léèrè, wí pé, Ta ni ẹ ń wá Wọ́n sì wí pé, Jésù ti Násárétì Jésù dáhùn pé, Mo ti wí fún yín pé, èmi nìyí ǹjẹ́ bí èmi ni ẹ bá ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa lọ Kí ọ̀rọ̀ nì kí ó lè ṣẹ, èyí tó wí pé, Àwọn tí ìwọ fi fún mi, èmi kò sọ ọ̀kan nù nínú wọn Nígbà náà ni Símónì Pétérù ẹni tí ó ní idà, fà á yọ, ó sì sá ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ké etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù Orúkọ ìránṣẹ́ náà amá a jẹ́ Mákọ́ọ̀sì Nítorí náà Jésù wí fún Pétérù pé, Tẹ idà rẹ bọ inú àkọ̀ rẹ ago tí baba ti fi fún mi, èmi ó ṣe aláìmu ún bí Nígbà náà ni ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àti olórí ẹ̀sọ́, àti àwọn oníṣẹ́ àwọn Júù mú Jésù, wọ́n sì dè é Wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sọ́dọ̀ Ánnà nítorí òun ni àna Káyáfà, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà Káyáfà sáà ni ẹni tí ó ti bá àwọn Júù gbìmọ̀ pé, ó ṣàǹfàní kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn Símónì Pétérù sì ń tọ Jésù lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mímọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jésù wọ ààfin olórí àlùfáà lọ Ṣùgbọ́n Pétérù dúró ní ẹnu ọ̀nà lóde Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mímọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùsọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Pétérù wọlé Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà wí fún Pétérù pé, Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí Ó wí pé, Èmi kọ́ Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn alaṣẹ́ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí òtútù mú, wọ́n sì ń yáná Pétérù sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná Nígbà náà ni olórí àlùfáà bi Jésù léèrè ní ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ní ti ẹ̀kọ́ rẹ̀ Jésù dá a lóhùn pé, Èmi ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé nígbà gbogbo ni èmi ń kọ́ni nínú Sínágọ́gù, àti ní Tẹ́ḿpìlì níbi tí gbogbo àwọn Júù ń pé jọ sí èmi kò sì sọ ohun kan ní ìkọ̀kọ̀ Èé ṣe tí ìwọ fi ń bi mí léèrè Béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ohun tí mo wí fún wọn wò ó, àwọn wọ̀nyí mọ ohun tí èmi wí Bí ó sì ti wí èyí tan, ọ̀kan nínú àwọn alasẹ́ tí ó dúró tì í fi ọwọ́ rẹ̀ lu Jésù, pé, Olórí àlùfáà ni ìwọ ń dá lóhùn bẹ́ẹ̀ Jésù dá a lóhùn pé, Bí mo bá sọ̀rọ̀ búburú, jẹ́rìí sí búburú náà ṣùgbọ́n bí rere bá ni, èé ṣe tí ìwọ fi ń lù mí Nítorí Ánnà rán an lọ ní dídè sọ́dọ̀ Káyáfà olórí àlùfáà Ṣùgbọ́n Símónì Pétérù dúró, ó sì ń yáná Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Ó sì ṣẹ́, wí pé, Èmi kọ́ Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Pétérù gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá Pétérù tún ṣẹ́ lójú kan náà àkùkọ sì kọ Nígbà náà, wọ́n fa Jésù láti ọ̀dọ̀ Káyáfà lọ sí ibi gbọ̀ngàn ìdájọ́ ó sì jẹ́ kùtùkùtù òwúrọ̀ àwọn tìkara wọn kò wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́, kí wọn má ṣe di aláìmọ́, ṣùgbọ́n kí wọn lè jẹ àsè ìrékọjá Nítorí náà Pílátù jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí pé, Ẹ̀sùn kín ní ẹ̀yin mú wá sí ọkùnrin yìí Wọ́n sì dáhùn wí fún un pé, Ìbá má ṣe pé ọkùnrin yìí ń hùwà ibi, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́ Nítorí náà Pílátù wí fún wọn pé, Ẹ mú un tìkára yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin yín Nítorí náà ni àwọn Júù wí fún un pé, Kò tọ́ fún wa láti pa ẹnikẹ́ni Kí ọ̀rọ̀ Jésù ba à lè ṣẹ, èyí tí ó sọ tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú Nítorí náà Pílátù tún wọ inú gbọ̀ngàn, ìdájọ́ lọ, ó sì pe Jésù, ó sì wí fún un pé, Ìwọ há ni a ni Ọba àwọn Júù bí Jésù dáhùn pé, Èrò ti ara rẹ ni èyí, tàbí àwọn ẹlòmíràn sọ ọ́ fún ọ nítorí mi Pílátù dáhùn wí pé, Èmi ha jẹ́ Júù bí Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè rẹ, àti àwọn olórí àlùfáà ni ó fà ọ́ lé èmi lọ́wọ́ kín ní ìwọ ṣe Jésù dáhùn wí pé, Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí ìbáṣe pé ìjọba mi jẹ́ ti ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ìbá jà, kí a má baà fi mí lé àwọn Júù lọ́wọ́ ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba mi kì í ṣe láti ìhín lọ Nítorí náà Pílátù wí fún un pé, Ọba ni ó nígbà náà Jésù dáhùn wí pé, Ìwọ wí pé, Ọba ni èmi jẹ́ Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi Pílátù wí fún un pé, Kín ni òtítọ́ Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní àṣà kan pé, kí èmi dá ọ̀kan sílẹ̀ fún yín nígbà àjọ ìrékọjá nítorí náà ẹ ó ha fẹ́ kí èmi dá Ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí Nítorí náà gbogbo wọn tún kígbe pé, Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Bárábà! Ọlọ́sà sì ni Bárábà A Dá Jésù Lébí Láti Kàn Mọ Àgbélébùú Nítorí náà ni Pílátù mú Jésù, ó sì nà án Àwọn ọmọ ogun sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí, wọ́n sì fi aṣọ ìgúnwà elésèé àlùkò wọ̀ ọ́ Wọ́n sì wí pé, Kábíyèsí, ọba àwọn Júù! Wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a ní ojú Pílátù sì tún jáde, ó sì wí fún wọn pé, Wò ó, mo mú u jáde tọ̀ yín wá, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé, èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀ Nítorí náà Jésù jáde wá, ti òun ti adé ẹ̀gún àti aṣọ elésèé àlùkò Pílátù sì wí fún wọn pé, Ẹ wò ọkùnrin náà! Nítorí náà nígbà tí àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn oníṣẹ́ rí i, wọ́n kígbe wí pé, Kàn án mọ́ àgbélébùú, kàn án mọ́ àgbélébùú Pílátù wí fún wọn pé, Ẹ mú un fún ara yín, kí ẹ sì kàn án mọ́ àgbélébùú nítorí èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ Àwọn Júù dá a lóhùn wí pé, Àwa ní òfin kan, àti gẹ́gẹ́ bí òfin, wa ó yẹ fún un láti kú, nítorí ó gbà pé ọmọ Ọlọ́run ni òun ń ṣe Nítorí náà nígbà tí Pílátù gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á Ó sì tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì wí fún Jésù pé, Níbo ni ìwọ ti wá Ṣùgbọ́n Jésù kò dá a lóhùn Nítorí náà, Pílátù wí fún un pé, Èmi ni ìwọ kò fọhùn sí Ìwọ kò mọ̀ pé, èmi ní agbára láti dá ọ sílẹ̀, èmi sì ní agbára láti kàn ọ́ mọ́ àgbélébùú Jésù dá a lóhùn pé, Ìwọ kì bá tí ní agbára kan lórí mi, bí kò se pé a fi í fún ọ láti òkè wá nítorí náà ẹni tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ ni ó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ jù Nítorí èyí Pílátù ń wá ọ̀nà láti dá a sílẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, wí pé, Bí ìwọ bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í se ọ̀rẹ́ Késárì ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ara rẹ̀ ní ọba, ó sọ̀rọ̀ òdì sí Késárì Nítorí náà nígbà tí Pílátù gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Jésù jáde wá, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ ní ibi tí a ń pè ní Òkúta-títẹ́, ṣùgbọ́n ní èdè Hébérù, Gábátà Ó jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ Àjọ-ìrékọjá, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí ẹ̀kẹfà Ó sì wí fún àwọn Júù pé, Ẹ wo ọba yín! Nítorí náà wọ́n kígbe wí pé, Mú un kúrò, mú un kúrò Kàn án mọ́ àgbélébùú Pílátù wí fún wọn pé, Èmi yóò ha kan ọba yín mọ́ àgbélébùú bí Àwọn olórí àlùfáà dáhùn wí pé, Àwa kò ní ọba bí kò ṣe Kábíyèsí Nítorí náà ni ó fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́ àgbélébùú Nítorí náà, wọ́n mú Jésù, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnra rẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Hébérù tí à ń pè ní Gọlígọtà Níbití wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, níhà ìhín àti níhà kejì, Jésù sì wà láàárin Pílátù sì kọ ìwé kan pẹ̀lú, ó sì fi í lé e lórí àgbélébùú náà Ohun tí a sì kọ ni, JÉSÙ TI NÁSÁRẸ́TÌ ỌBA ÀWỌN JÚÙ Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ó ka ìwé àkọlé yìí nítorí ibi tí a gbé kan Jésù mọ́ àgbélébùú sún mọ́ etí ìlú a sì kọ ọ́ ní èdè Hébérù àti Látìnì, àti ti Gíríkì Nítorí náà àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù wí fún Pílátù pé, Má ṣe kọ, Ọba àwọn Júù ṣùgbọ́n pé ọkùnrin yìí wí pé, èmi ni Ọba àwọn Júù Pílátù dáhùn pé, ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́ Nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun, nígbà tí wọ́n kan Jésù mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apákan fún ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúrán, wọ́n hun ún láti òkè títí jáde Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀ Ti ẹni tí yóò jẹ́ kí ìwé-mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé, Wọ́n pín aṣọ mi láàárin ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ogun ṣe Ìyá Jésù àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Màríà aya Kílópà, àti Màríà Magidalénì sì dúró níbi àgbélébùú, Nígbà tí Jésù rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ-ẹ̀yìn náà dúró, ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, Obìnrin, wo ọmọ rẹ! Lẹ́yìn náà ni ó sì wí fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, Wo ìyá rẹ! Láti wákàtí náà lọ ni ọmọ-ẹ̀yìn náà sì ti mú un lọ sí ilé ara rẹ̀ Lẹ́yìn èyí, bí Jésù ti mọ̀ pé, a ti parí ohun gbogbo tán, kí ìwé mímọ́ bà á lè ṣẹ, ó wí pé, Òrùngbẹ ń gbẹ mí Ohun èlò kan tí ó kún fún ọtí kíkan wà níbẹ̀, wọ́n tẹ kànrìnkàn bọ inú rẹ̀, wọ́n sì fi lé ori igi híssópù, wọ́n sì nà án sí i lẹ́nu Nígbà tí Jésù sì ti gba ọtí kíkan náà, ó wí pé, Ó parí! Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ Nítorí ó jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, kí òkú wọn má baà wà lórí àgbélébùú ní ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, àwọn Júù bẹ Pílátù pé kí a ṣẹ́ egungun itan wọn, kí a sì gbé wọn kúrò Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun wá, wọ́n sì ṣẹ́ egungun itan ti èkínní, àti ti èkejì, tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, tí wọ́n sì rí i pé ó ti kú, wọn kò ṣẹ́ egungun itan rẹ̀ Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, lójú kan náà, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde Ẹni tí ó rí sì jẹ́rìí, òtítọ́ sì ni ẹ̀rí rẹ̀ ó sì mọ̀ pé òótọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin baà lè gbàgbọ́ Nǹkan wọ̀nyí ṣe, kí ìwé mímọ́ ba à lè ṣẹ, tí ó wí pé, A kì yóò fọ́ egungun rẹ̀ Ìwé mímọ́ mìíràn pẹ̀lú sì wí pé, Wọn ó máa wo ẹni tí a gún lọ́kọ̀ Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ní Jóṣéfù ará Arimatíyà, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jésù, ṣùgbọ́n ní ìkọ̀kọ̀, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, o bẹ Pílátù kí òun lè gbé òkú Jésù kúrò Pílátù sì fún un ní àṣẹ Nígbà náà ni ó wá, ó sì gbé òkú Jésù lọ Níkodémù pẹ̀lú sì wá, ẹni tí ó tọ Jésù wá lóru lákọ́kọ́, ó sì mú àdàpọ̀ òjíá àti álóè wá, ó tó ìwọ̀n ọgọ́rún lítà Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú Jésù, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í pẹ̀lú tùràrí, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn Júù ti rí ní ìsìnkú wọn Àgbàlá kan sì wà níbi tí a gbé kàn án mọ́ àgbélébùú ibojì titun kan sì wà nínú àgbàlá náà, nínú èyí tí a kò tíì tẹ́ ẹnìkan sí rí Ǹjẹ́ níbẹ̀ ni wọ́n sì tẹ́ Jésù sí, nítorí ìpalẹ̀mọ́ àwọn Júù nítorí ibojì náà wà nítòòsí Jésù Sọ Omi Di Ọtí Wáìnì Ní ọjọ́ kẹ́ta, a ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kánà ti Gálílì Ìyá Jésù sì wà níbẹ̀, A sì pe Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi ìgbéyàwó náà Nígbà tí wáìnì sì tán, ìyá Jésù wí fún un pé, Wọn kò ní wáìnì mọ́ Jésù fèsì pé, Arábìnrin ọ̀wọ́n, èése tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí Àkókò mi kò tí ì dé Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ogójì gálọ́ọ̀nù Jésù wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí Lẹ́yìn náà ni ó wí fún wọn pé, Ẹ bù jáde lára rẹ̀ kí ẹ sì gbé e tọ olórí àsè lọ Wọ́n sì gbé e lọ Olórí àsè náà tọ́ omi tí a sọ di wáìnì wò Òun kò sì mọ ibi tí ó ti wá, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tí ó bu omi náà wá mọ̀ Olórí àsè sì pe ọkọ ìyàwó sí apákan, Ó sì wí fún un pé, Olúkúlùkù a máa kọ́kọ́ gbé wáìnì tí ó dára jùlọ kalẹ̀ nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì mu ún yó tan, nígbà náà níí wọ́n a mú èyí tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ wá ṣùgbọ́n ìwọ ti pa wáìnì dáradára yìí mọ́ títí ó fi di ìsinyìí Èyí jẹ́ àkọ́se iṣẹ́ àmì rẹ̀, tí Jésù ṣe ní Kánà ti Gálílì Ó sì fi ògo rẹ̀ hàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́ Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kápérnámù, Òun àti Ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ́n sì gbé ibẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́ Àjọ-ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, Jésù sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù, Ó sì rí àwọn tí n ta màlúù, àti àgùntàn, àti àdàbà, àti àwọn onípàsípàrọ̀ owó ní tẹ́ḿpìlì wọ́n jòko Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹ́ḿpílì, àti àgùntàn àti màlúù ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó sì bi tábìlì wọn ṣubú Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhín ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, Ìtara ilé rẹ jẹ mí run Nígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, Àmì wo ni ìwọ lè fi hàn wá, tí ìwọ fi ń se nǹkan wọ̀nyí Jésù dáhùn ó sì wí fún wọn pé, Ẹ wó tẹ́ḿpílì yìí palẹ̀, Èmi ó sì tun un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, Ọdún mẹ́rìndíláàdọ́ta ni a fi kọ́ tẹ́ḿpílì yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ijọ́ mẹ́ta Ṣùgbọ́n Òun ń sọ ti tẹ́ḿpílì ara rẹ̀ Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn wọ́n sì gba ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jésù ti sọ gbọ́ Nígbà tí ó sì wà ní Jérúsálẹ́mù, ní àjọ-ìrékọjá, lákókò àjọ náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì tí ó ṣe Ṣùgbọ́n Jésù kò gbé ara lé wọn, nítorí tí ó mọ gbogbo ènìyàn Òun kò sì nílò ẹ̀rí nípa ènìyàn nítorí tí Ó mọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ènìyàn Òfo Ibojì Ní ọjọ́ kínní ọ̀ṣẹ̀ kùtùkùtù nígbà tí ilẹ̀ kò tíì mọ́ ni Màríà Magídalénè wá sí ibojì, ó sì rí i pé, a ti gbé òkúta kúrò lẹ́nu ibojì Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Símónì Pétérù wá, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí Nígbà náà ni Pétérù jáde, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, wọ́n sì wá sí ibojì Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré èyí ọmọ-ẹ̀yìn sì sáré ya Pétérù, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀ ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀ Nígbà náà ni Símónì Pétérù tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀ Àti pé, gèlè tí ó wà níbi orí rẹ̀ kò sì wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ṣùgbọ́n o ká jọ ní ibìkan fúnra rẹ̀ Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, ẹni tí ó kọ́ dé ibojì wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì rí i ó sì gbàgbọ́ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sì tún padà lọ sí ilé wọn Ṣùgbọ́n Màríà dúró létí ibojì lóde, ó ń sọkún bí ó ti ń ṣọkún, bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀, ó sì wo inú ibojì Ó sì kíyèsí àwọn áńgẹ́lì méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jésù gbé ti sùn sí Wọ́n sì wí fún un pé, Obìnrin yìí, èé ṣe tí ìwọ fi ń sọkún Ó sì wí fún wọn pé, Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó yípadà, ó sì rí Jésù dúró, kò sì mọ̀ pé Jésù ni Jésù wí fún un pé, Obìnrin yìí, èé ṣe tí ìwọ fi ń sọkún Ta ni ìwọ ń wá Òun ṣebí olùsọ́gbà ní í ṣe, ó wí fún un pé, Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn yìí, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi ó sì gbé e kúrò Jésù wí fún un pé, Màríà! Ó sì yípadà, ó wí fún un pé, Rábónì! Jésù wí fún un pé, Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí nítorí tí èmi kò tíì gókè lọ sọ́dọ̀ Baba mi ṣùgbọ́n, lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi, àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín   Màríà Magídalénè wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Òun ti rí Olúwa! Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun Lọ́jọ́ kan náà, lọ́jọ́ kínní ọ̀ṣẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jésù dé, ó dúró láàárin, ó sì wí fún wọn pé, Àlàáfíà fún yín Nígbà tí ó sì ti wí bẹ́ẹ̀ tán, ó fi ọwọ́ àti ìhà rẹ̀ hàn wọ́n Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yọ̀, nígbà tí wọ́n rí Olúwa Nítorí náà, Jésù sì tún wí fún wọn pé, Àlàáfíà fún yín gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán yín Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó mí sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ gba Ẹ̀mí mímọ́! Ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá fi jì, a fi jì wọ́n ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá dá dúró, a dá wọn dúró Ṣùgbọ́n Tómásì, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, tí a ń pè ní Dídímù, kò wà pẹ̀lú wọn nígbà tí Jésù dé Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù wí fún un pé, Àwa ti rí Olúwa! Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, Bí kò ṣe pé mo bá rí àpá ìṣó ni ọwọ́ rẹ̀ kí èmi sì fi ìka mi sí àpá ìṣó náà, kí èmi sì fi ọwọ́ mi sí ìhà rẹ̀, èmi kì yóò gbàgbọ́! Lẹ́yìn ijọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tọ́másì pẹ̀lú wọn nígbà tí a sì ti ti ìlèkùn, Jésù dé, ó sì dúró láàrin, ó wí pé, Àlàáfíà fún yín Nígbà náà ni ó wí fún Tọ́másì pé, Mú ìka rẹ wá níhín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi sì mú ọwọ́ rẹ wá níhín, kí o sì fi sí ìhà mi kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ Tọ́másì dáhùn ó sì wí fún un pé, Olúwa mi àti Ọlọ́run mi! Jésù wí fún un pé, Nítorí tí ìwọ rí mi ni ìwọ ṣe gbàgbọ́ alábùkún fún ni àwọn tí kò rí mi, tí wọ́n sì gbàgbọ́! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì mìíràn ni Jésù ṣe níwájú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sínú ìwé yìí Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jésù ní í ṣe Kírísítì náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀ Jésù Àti Iṣẹ́ Ìyanu Ẹja Pípa Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù tún fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ létí òkun Tíbéríà báyìí ni ó sì farahàn Símónì Pétérù, àti Tọ́másì tí a ń pè ní Dídímù, àti Nátanáẹ́lì ará Kánà ti Gálílì, àti àwọn ọmọ Sébédè, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀ Símónì Pétérù wí fún wọn pé, Èmi ń lọ pẹja! Wọ́n wí fún un pé, Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, Jésù dúró létí òkun ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jésù ni Jésù wí fún wọn pé, Ẹ̀yin ọmọdé, ẹ ní oúnjẹ díẹ̀ bí Wọ́n dá a lóhùn pé, Rárá o Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ sọ àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ̀yin ó sì rí Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò sì lè fà á jáde nítorí ọ̀pọ̀ ẹja Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jésù fẹ́ràn wí fún Pétérù pé, Olúwa ni! Nígbà tí Símónì Pétérù gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú òkun Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù mú ọkọ̀ ojú omi kékeré kan wá nítorí tí wọn kò jìnà sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ìwọ̀n igba ìgbọ̀nwọ́ wọ́n ń wọ́ àwọ̀n náà tí ó kún fún ẹja Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹ̀yinná níbẹ̀ àti ẹja lórí rẹ̀ àti àkàrà Jésù wí fún wọn pé, Ẹ mú nínú ẹja tí ẹ pa nísinsin yìí wá Nítorí náà Símónì Pétérù gòkè, ó sì fa àwọ̀n náà wálẹ̀, ó kún fún ẹja ńlá, ó jẹ́ mẹ́taléláádọ́jọ bí wọ́n sì ti pọ̀ tó náà, àwọ̀n náà kò ya Jésù wí fún wọn pé, Ẹ wá jẹun òwúrọ̀ Kò sì sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ́ bí i pé, Ta ni ìwọ jẹ́ Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni Jésù wá, ó sì mú àkàrà, ó sì fi fún wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹja Èyí ni Ìgbà kẹ́ta nísinsin yìí tí Jésù farahan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú Ǹjẹ́ lẹ́yìn, ìgbà tí wọ́n jẹun òwúrọ̀ tan, Jésù wí fún Símónì Pétérù pé, Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí Ó sì wí fún un pé, Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ Ó wí fún un pé, Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, Símónì ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ mi bí Ó wí fún un pé, Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ Ó wí fún un pé, Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi Ó wí fún un nígbà kẹ́ta pé, Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ràn mi bí Inú Pétérù sì bàjẹ́, nítorí tí ó wí fún un nígbà ẹ̀kẹ́ta pé, Ìwọ fẹ́ràn mi bí Ó sì wí fún un pé, Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ Jésù wí fún un pé, Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, nígbà tí ìwọ wà ní ọ̀dọ́mọdé, ìwọ a máa di ara rẹ ní àmùrè, ìwọ a sì máa rìn lọ sí ibi tí ìwọ bá fẹ́ ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá di arúgbó, ìwọ ó na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ ní àmùrè, yóò mú ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́ Lẹ́yìn ìgbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó wí fún un pé, Máa tọ̀ mí lẹ́yìn Pétérù sì yípadà, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn náà, ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ń bọ̀ lẹ́yìn ẹni tí ó fararọ̀ súnmọ́ àyà rẹ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́ tí ó sì wí fún un pé, Olúwa, ta ni ẹ̀ni tí ó fi ọ́ hàn Nígbà tí Pétérù rí i, ó wí fún Jésù pé, Olúwa, Eléyìí ha ńkọ́ Jésù wí fún un pé, Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kínni èyí jẹ́ sí ọ Ìwọ máa tọ̀ mí lẹ́yìn Ọ̀rọ̀ yìí sì tàn ká láàrin àwọn arákùnrin pé, ọmọ-ẹ̀yìn náà kì yóò kú ṣùgbọ́n Jésù kò wí fún un pé, Òun kì yóò kú ṣùgbọ́n, Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kínni èyí jẹ́ sí ọ Èyí ni ọmọ-ẹ̀yìn náà, tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí àwa sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun mìíràn pẹ̀lú ni Jésù ṣe, èyí tí bí a bá kọ̀wé wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé gbogbo ayé pàápàá kò lè gba ìwé náà tí a bá kọ ọ́ Àmín Jésù Kọ́ Nikodémù Ọkùnrin kan sì wà nínú àwọn Farisí, tí a ń pè ní Níkódémù, ìjòyè kan láàrin àwọn Júù Òun náà ní ó tọ Jésù wá ní òru, ó sì wí fún un pé, Rábì, àwa mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ìwọ ń ṣe nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ àmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe, bí kò se pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ Jésù dáhùn ó sì wí fún un pé, Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a tún ènìyàn bí, òun kò lè rí ìjọba Ọlọ́run Nikodémù wí fún un pé, a ó ti ṣe lè tún ènìyàn bí nígbà tí ó di àgbàlagbà tan Ó ha lè wọ inú ìyá rẹ̀ lọ nígbà kejì, kí a sì bí i Jésù dáhùn wí pé, Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a fi omi àti Ẹ̀mí bí ènìyàn, òun kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run Èyí tí a bí nípa ti ara, ti ara ni èyí tí a sì bí nípa ti Ẹ̀mí, ti ẹ̀mí ni Kí ẹnu kí ó má ṣe yà ọ́, nítorí mo wí fún ọ pé, A kò lè ṣe aláìtún yín bí Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí bi tí ó gbé wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó gbé ti wá, àti ibi tí ó gbé ń lọ gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa ti Ẹ̀mí Nikodémù dáhùn, ó sì wí fún un pé, Nǹkan wọ̀nyí yóò ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀ Jésù dáhùn, ó sì wí fún un pé, Ṣé olùkọ́ni ní Ísírẹ́lì ni ìwọ ń ṣe, o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Àwa ń sọ èyí tí àwa mọ̀, a sì ń jẹ́rìí èyí tí àwa ti rí ẹ̀yin kò sì gba ẹ̀rí wa Bí mo bá sọ ohun ti ayé yìí fún yín, tí ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ ohun ti ọ̀run fún yín Kò sì sí ẹni tí ó gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, Ọmọ Ènìyàn tí ń bẹ ní ọ̀run Bí Móse sì ti gbé ejò sókè ní ihà, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ-Ènìyàn sókè pẹ̀lú Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, kí ó má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó le ní iyè àìnípẹ̀kun Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, tí ó fi ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní iyè àìnípẹ̀kun Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́ ṣùgbọ́n kí a le ti ipaṣẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là Ẹni tí ó bá gbà á gbọ́, a kò ní dá a lẹ́jọ́ ṣùgbọ́n a ti dá ẹni tí kò gbà á gbọ́ lẹ́jọ́ ná, nítorí tí kò gba orúkọ ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run gbọ́ Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú níí ìkórìíra ìmọ́lẹ̀, kìí sí wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a má ṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ níí wá sí ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè fi ara hàn pé a ṣe wọ́n nípa ti Ọlọ́run Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Jùdíà ó sì dúró pẹ̀lú wọn níbẹ̀ ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún ni Jòhánù pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Áhínónì, ní agbégbé Sálímù, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀ wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọmi Nítorí tí a kò tí ì sọ Jòhánù sínú túbú Nígbà náà ni iyàn kan wà láàárin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù, àti Júù kan nípa ti ìwẹ̀nù Wọ́n sì tọ Jòhánù wá, wọ́n sì wí fún un pé, Rábì, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jọ́dánì, tí ìwọ ti jẹ́rí rẹ̀, wò ó, òun tẹ ni bọmi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá Jòhánù dáhùn ó sì wí pé, Ènìyàn kò le rí ǹkankan gbà, bí kò ṣepé a bá ti fi fún ún láti ọ̀run wá Èyin fúnra yín jẹ́rìí mi, pé mo wí pé, Èmi kì í ṣe Kírísítì náà, ṣùgbọ́n pé a rán mi ṣíwájú rẹ̀ Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàì má relẹ̀ Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀ kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olótìítọ́ ni Ọlọ́run Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́ Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun ẹni tí kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yóò rí ìyè nítorí ìbínú Ọlọ́run ń bẹ lórí rẹ̀ Jésù Sọ̀rọ̀ Pẹ̀lú Obìnrin Ara Samáríà Àwọn Farisí sì gbọ́ pé, Jésù ni, ó sì n ṣe ìtẹ̀bọmi fún àwọn ọmọ ẹyìn púpọ̀ ju Jóhánù lọ, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù tìkararẹ̀ kò ṣe ìtẹ̀bọmibí kò ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Nígbà tí Olúwa mọ nípa èyí, Ó fi Jùdéà sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Gálílì lẹ́ẹ̀kan si Òun sì ní láti kọjá láàárin Samaríà Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaríà kan, tí a ń pè ní Síkárì, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jákọ́bù ti fi fún Jóṣéfù, ọmọ rẹ̀ Kànga Jákọ́bù sì wà níbẹ̀ Nítorí pé ó rẹ Jésù nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jòkó létí kànga ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́ Obìrin kan, ará Samaríà sì wá láti fà omi Jésù wí fún un pé fún mi mu Obìnrin ará Samáríà náà sọ fún un pé, Júù ni ẹ́ obìnrin ará Samáríà ni èmi Eéti rí tí ìwọ ń bèèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi Jésù dáhùn, ó sì wí fún un pé, Ìbáṣepé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, fún mi mu, ìwọ ìbá sì ti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, Òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ Obìnrin náà wí fún un pé, Alàgbà, ìwọ kò ní nǹkan tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jìn Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà Ìwọ pọ̀ ju Jákọ́bù baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí Òun tìkararẹ̀ mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran rẹ̀ Jésù dáhùn, ó sì wí fún un pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òrùngbẹ yóò tún gbẹ ẹ́ Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fí fún un, òrùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun títí ayérayé Obìnrin náà sì wí fún u pé, Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òùngbẹ kí ó má se gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá máa pọn omi níbí Jésù wí fún un pé, Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí Òbìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, Èmi kò ní ọkọ Jésù wí fún un pé, Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí ọkùnrin tí ìwọ sì ní bá yìí kì í ṣe ọkọ rẹ Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni Obìnrin náà wí fún un pé, Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe Àwọn bàbá wa sìn lórí òkè yìí ẹ̀yin sì wí pé, Jérúsálẹ́mù ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn Jésù wí fún un pé, Gbà mí gbọ́, obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò se lórí òke yìí tàbí ní Jérúsálẹ́mù ni ẹ̀yin ó máa sin Baba Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀ àwa ń sin ohun tí àwa mọ̀ nítorí ìgbàlà ti ọ̀dọ̀ àwọn Júù wá Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsìn yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́ nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun Ẹ̀mí ni Ọlọ́run àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́ Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, Mèsáyà ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Krísítì Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa Jésù sọ ọ́ di mímọ̀ fún un pé, Èmi ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Òun Lórí èyí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kan tí ó wí pé, Kíni ìwọ ń wá tàbí Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀ Nígbà náà ni obìnrin náà fi ládugbó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi èyí ha lè jẹ́ Krísítì náà Nígbà náà ni wọ́n ti ìlú jáde, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá Láàárin èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, Olùkọ́, jẹun Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, Èmi ní ońjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀ Nítorí náà ni àwọn ọmọ-èyìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, Ẹnì kan mú ońjẹ fún un wá láti jẹ bí Jésù wí fún wọn pé, Ońjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀ Ẹ̀yin kò ha wí pé, Ó ku oṣù mẹ́rin, ìkọ́rè yóò sì dé Wò ó, mo wí fún un yín, Ẹ sí ojú yín sókè, kí ẹ sì wo oko nítorí tí wọn ti pọ́n fún ìkórè Kódà báyìí, ẹni tí ó ń kórè ń gba owó ọ̀yà rẹ̀, kódà báyìí, ó ń kórè fún ayérayé kí ẹni tí ó ń fúrúgìn àti ẹni tí ń kórè lè jọ máa yọ̀ pọ̀ Nítorí nínú èyí ni ọ̀rọ̀ náà fi jẹ́ òtítọ́ Ẹnì kan ni ó fúrúgbìn, ẹlòmíràn ni ó sì ń kórè jọ Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samáríà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn ó sì dúró fún ijọ́ méjì Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́ nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Krísítì náà, Olùgbàlà aráyé Lẹ́yìn ijọ́ méjì ó sì ti ibẹ̀ kúrò, ó lọ sí Gálílì Nítorí náà nígbà tí ó dé Gálílì, àwọn ará Gálílì gbà á, nítorí ti wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ṣe ní Jérúsálẹ́mù nígbà àjọ nítorí àwọn tìkára wọn lọ sí àjọ pẹ̀lú Bẹ́ẹ̀ ni Jésù tún wá sí Kánà ti Gálílì, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kápérnámù Nígbà tí ó gbọ́ pé Jésù ti Jùdéà wá sí Gálílì, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá nítorí tí ó wà ní ojú ikú Nígbà náà ni Jésù wí fún u pé, Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí àmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú Jésù wí fún un pé, Má a bá ọ̀nà rẹ lọ ọmọ rẹ yóò yè Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàde rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, Ní àná, ní wákàtí kéje ni ibà náà fi í sílẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni baba náà mọ̀ pé ọmọ rẹ̀ yè Òun tìkara rẹ̀ sì gbàgbọ́, àti gbogbo ilé rẹ̀ Èyí ni iṣẹ́ àmì kéjì tí Jésù ṣe nígbà tí ó ti Jùdéà jáde wá sí Gálílì Ìwòsàn Ní Etí Odò Adágún Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, àjọ àwọn Júù kan kò Jésù sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù Adágún omi kan sì wà ní Jérúsálẹ́mù, létí bodè àgùntàn, tí a ń pè ní Bẹtiṣáídà ní èdè Hébérù, tí ó ní ìloro márùn-ún Ní ẹ̀gbẹ́ odò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn abirùn ènìyàn máa ń gbé dúbúlẹ̀ sí, àwọn afọ́jú, arọ àti alárùn ẹ̀gbà, wọ́n sì ń dúró de rírú omi Nítorí angẹ́lì a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sínú adágún náà, a sì máa rú omi rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti rú omi náà tan ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ wọ inú rẹ̀ a di alára dídá kúrò nínú àrùnkárùn tí ó ní Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjìdínlógójì Bí Jésù ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí Abirùn náà dá a lóhùn wí pé, Arákùnrin, èmi kò ní ẹni tí ìbá gbé mi sínú adágún, nígbà tí a bá ń rú omi náà bí èmi bá ti ń bọ̀ wá, ẹlòmíràn a sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀ ṣíwájú mi Jésù wí fún un pé, Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn Lọ́gán, a sì mú ọkùnrin náà láradá, ó sì gbé àkéte rẹ̀, ó sì ń rìn Ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ ìsinmi Nítorí náà àwọn Júù wí fún ọkùnrin náà tí a mú láradá pé, Ọjọ́ ìsinmi ni òní kò tọ́ fún ọ láti gbé àkéte rẹ Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, Ẹni tí ó mú mi láradá, ni ó wí fún mi pé, Gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn   Nígbà náà ni wọ́n bi í lérè wí pé, Ọkùnrin wo ni ẹni tí ó wí fún ọ pé gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn Ẹni tí a mú láradá náà kò sì mọ̀ ẹni tí ó jẹ́ nítorí Jésù ti kúrò níbẹ̀, àwọn ènìyàn púpọ̀ wà níbẹ̀ Lẹ́yìn náà, Jésù rí i ní tẹ́ḿpìlì ó sì wí fún un pé, Wò ó, a mú ọ láradá má se dẹ́sẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ! Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé, Jésù ni ẹni tí ó mú òun láradá Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jésù, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí Ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn pé, Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́ Nítorí èyí ni àwọn Júù túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, kì í ṣe nítorí pé ó ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó wí pẹ̀lú pé, Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó ń mú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba Nígbà náà ni Jésù dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò se ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú Nítorí Baba fẹ́ràn ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án, òun yóò sì fi iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di alàyè bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di alàyè pẹ̀lú Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́ Kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun, òun kì yóò sì wá sí ìdájọ́ ṣùgbọ́n ó ti ré ikú kọjá bọ́ sí ìyè Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsìn yìí, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn ọmọ Ọlọ́run àwọn tí ó bá gbọ́ yóò sì yè Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó sì fi fún ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀ Ó sì fún un ní àsẹ láti máa ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú, nítorí tí òun jẹ́ ọmọ ènìyàn Kí èyí má ṣe yà yín lẹ́nu nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní ibojì yóò gbọ́ ohun rẹ̀ Wọn ó sì jáde wá àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè àwọn tí ó sì ṣe búburú sí àjíǹde ìdájọ́ Èmi kò le ṣe ohun kan fún ara mi bí mo ti ń gbọ́, mo ń dájọ́ òdodo sì ni ìdájọ́ mi nítorí èmi kò wá ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò se ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi Bí èmi bá ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òtítọ́ Ẹlòmíràn ni ẹni tí ń jẹ́rìí mi èmi sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹrí mi tí ó jẹ́ Ẹ̀yin ti ránsẹ́ lọ sọ́dọ̀ Jòhánù, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́ Ṣùgbọ́n èmi kò gba jẹ̀rìí lọ́dọ̀ ènìyàn nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀ ẹ̀yin sì fẹ́ fún sáà kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó pọ̀ju ti Jòhánù lọ nítorí iṣẹ́ tí Baba ti fi fún mi láti ṣe parí, iṣẹ́ náà pàápàá tí èmi ń ṣe náà ń jẹ́rí mi pé, Baba ni ó rán mi Àti Baba tìkárarẹ̀ tí ó rán mi ti jẹ́rí mi Ẹ̀yin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò rí ìrísí rẹ̀ Ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti máa gbé inú yín nítorí ẹni tí ó rán, òun ni ẹ̀yin kò gbàgbọ́ Ẹ̀yin ń wá ìwé-mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rí mi Ẹ̀yin kò sì fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin baà lè ní ìyè Èmi kò gba ògo lọ́dọ̀ ènìyàn Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé, ẹ̀yin fúnra yín kò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò sì gbà mí bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, òun ni ẹ̀yin yóò gbà Ẹ̀yin ó ti ṣe lè gbàgbọ́, ẹ̀yin tí ń gba ògo lọ́dọ̀ ara yín tí kò wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan wá Ẹ má ṣe rò pé, èmi ó fi yín sùn lọ́dọ̀ Baba ẹni tí ń fi yín sùn wà, àní Mósè, ẹni tí ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lẹ́ Nítorí pé ẹ̀yin ìbá gba Mósè gbọ́, ẹ̀yin ìbá gbà mí gbọ́ nítorí ó kọ ìwé nípa tẹ̀mi Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gba ìwé rẹ̀ gbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbà ọ̀rọ̀ mi gbọ́ Jésù Bọ́ Ẹgbẹ̀rún Márùnún Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù kọjá sí apákejì òkun Gálílì, tí í ṣe òkun Tiberíà Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn Jésù sì gun orí òkè lọ, níbẹ̀ ni ó sì gbé jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ Àjọ ìrékọjá ọdún àwọn Júù sì sún mọ́ etílé Ǹjẹ́ bí Jésù ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Fílípì pé, Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ Ó sì sọ èyí láti dán an wò nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ohun tí òun ó ṣe Fílípì dá a lóhùn pé, Àkàrà igba owó idẹ kò lè tó fún wọn, bí olúkúlùkù wọn kò tilẹ̀ níí rí ju díẹ̀ bù jẹ Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ańdérù, arákùnrin Símónì Pétérù wí fún un pé, Ọmọdékùnrin kan ńbẹ níhínyìí, tí ó ní ìṣù àkàrà barle márùnún àti ẹja kékèké méjì ṣùgbọ́n kín ni ìwọ̀nyí jẹ́ láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí Jésù sì wí pé, Ẹ mú kí àwọn ènìyàn náà jókòó! Kóríkó púpọ̀ sì wá níbẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin náà jókòó ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní iye Jésù sì mú ìṣù àkàrà náà Nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì pín wọn fún àwọn tí ó jókòó bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni ẹja ní ìwọn bí wọ́n ti ń fẹ́ Nígbà tí wọ́n sì yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Ẹ kó àjẹkù tí ó kù jọ, kí ohunkóhun má ṣe ṣòfò Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó wọn jọ wọ́n sì fi àjẹkù ìṣù àkàrà barle márùn-ún náà kún agbọ̀n méjìlá, èyí tí àwọn tí ó jẹun jẹ kù Nítorí náà nígbà tí àwọn ọkùnrin náà rí iṣẹ́-àmì tí Jésù ṣe, wọ́n wí pé, Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà tí ń bọ̀ wá sí ayé Nígbà tí Jésù sì wòye pé wọ́n ń fẹ́ wá fi agbára mú òun láti lọ fi jọba, ó tún padà lọ sórí òkè, òun nìkan Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí òkun Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá òkun lọ sí Kápénámù Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jésù kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn Òkun sì ń ru nítorí ẹ̀fúfù líle tí ńfẹ́ Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jésù ń rìn lórí òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà ẹ̀rù sì bà wọ́n Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, Èmi ni ẹ má bẹ̀rù Nítorí náà wọ́n fi ayọ̀ gbà á sínú ọkọ̀ lójúkannáà ọkọ̀ náà sì dé ilẹ̀ ibi tí wọ́n gbé ń lọ Ní ijọ́ kéjì nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó dúró ní apákejì òkun ríi pé, kò sí ọkọ̀ ojú omi mìíràn níbẹ̀, bí kò ṣe ọ̀kan náà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ̀, àti pé Jésù kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi náà, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni ó lọ Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ̀ ojú omi mìíràn ti Tiberíà wá, létí ibi tí wọn gbé jẹ àkàrà, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti dúpẹ́ Nítorí náà nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Jésù tàbí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, àwọn pẹ̀lú wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kápánámù, wọ́n ń wá Jésù Nígbà tí wọ́n sì rí i ní apákejì òkun, wọ́n wí fún un pé, Rábì, nígbà wo ni ìwọ wá síhín yìí Jésù dá wọn lóhùn ó sì wí pé, Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín Ẹ̀yin ń wá mi, kì í ṣe nítorí tí ẹ̀yin rí iṣẹ́-àmì, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀yin jẹ àjẹyó ìṣù àkàrà Ẹ má ṣe ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ńṣègbé, ṣùgbọ́n fún oúnjẹ tí ó wà títí di ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí ọmọ-ènìyàn yóò fi fún yín nítorí pé òun ni, àní Ọlọ́run Baba ti fi èdìdì dì í Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, Kín ni àwa ó ha ṣe, kí a lè ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run Jésù dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, Èyí ni iṣe Ọlọ́run pé, kí ẹ̀yin gba ẹni tí ó rán an gbọ́ Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, Iṣẹ́ àmì kín ní ìwọ ń ṣe, tí àwa lè rí, kí a sì gbà ọ́ gbọ́ Iṣẹ́ kínni ìwọ ṣe Àwọn baba wa jẹ mánà ní ihà gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, Ó fi oúnjẹ láti ọ̀run wá oúnjẹ fún wọn jẹ   Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kì í ṣe Mósè ni ó fi oúnjẹ fún yín láti ọ̀run wá ṣùgbọ́n Baba mi ni ó fi oúnjẹ òtítọ́ náà fún yín láti ọ̀run wá Nítorí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni èyí tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó sì fi ìyè fún aráyé Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí títí láé Jésù wí fún wọn pé, Èmi ni oúnjẹ ìyè ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òrùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Ẹ̀yin ti rí mi, ẹ kò sì gbàgbọ́ Gbogbo èyí tí Baba fi fún mi, yóò tọ̀ mí wá ẹni tí ó bá sì tọ̀ mí wá, èmi kì yóò tà á nù, bí ó tí wù kó rí Nítorí èmi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti má a ṣe ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi Èyí sì ni ìfẹ́ Baba tí ó rán mi pé ohun gbogbo tí o fi fún mi, kí èmi má ṣe sọ ọ̀kan nù nínú wọn, ṣùgbọ́n kí èmi lè jí i dìde níkẹyìn ọjọ́ Èyí sì ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo ọmọ, tí ó bá sì gbà á gbọ́, kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́ Nígbà náà ni àwọn Júù ń kùn sí i, nítorí tí ó wí pé, Èmi ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá Wọ́n sì wí pé, Jésù ha kọ́ èyí, ọmọ Jósẹ́fù, baba àti ìyá ẹni tí àwa mọ̀ Báwo ni ó ṣe wí pé, Èmi ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá Nítorí náà Jésù dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ má ṣe kùn láàárin yín! Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, bí kò ṣe pé Baba tí ó rán mi fà á Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́ A sáà ti kọ ọ́ nínú àwọn wòlíì pé, A ó sì kọ́ gbogbo wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́, tí a sì ti ọ̀dọ̀ Baba kọ́, òun ni ó ń tọ̀ mí wá Kì í ṣe pé ẹnìkan ti rí Baba bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, òun ni ó ti rí Baba Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun Èmi ni oúnjẹ ìyè Àwọn baba yín jẹ mánà ní ihà, wọ́n sì kú Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé oúnjẹ náà tí èmi ó sì fifúnni fún ìyè aráyé ni ara mi Nítorí náà ni àwọn Júù ṣe ń bá ara wọn jiyàn, pé, Ọkùnrin yìí yóò ti ṣe lè fi ara rẹ̀ fún wa láti jẹ Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá jẹ ara ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin kò ní ìyè nínú yin Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun Èmi o sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́ Nítorí ara mi ni ohun jíjẹ nítòótọ́, àti ẹ̀jẹ̀ mi ni ohun-mímu ní tòótọ́ Ẹni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ń gbé inú mi, èmi sì ń gbé inú rẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, tí èmi sì yè nípa Baba gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó jẹ mí, òun pẹ̀lú yóò yè nípa mi Èyí sì ni oúnjẹ náà tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá kì í ṣe bí àwọn baba yín ti jẹ mánà, tí wọ́n sì kú ẹni tí ó bá jẹ́ oúnjẹ yìí yóò yè láéláé Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ nínú sínágọ́gù, bí ó ti ń kọ́ni ní Kápánámù Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, Ọ̀rọ̀ tí ó le ni èyí ta ní lè gbọ́ ọ Nígbà tí Jésù sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn sí ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún wọn pé, Èyí jẹ́ ìkọ̀sẹ̀ fún yín bí Ǹjẹ́, bí ẹ̀yin bá sì rí i tí ọmọ ènìyàn ń gòkè lọ síbi tí ó gbé ti wà rí ń kọ́ Ẹ̀mi ní ń sọni di ààyè ara kò ní èrè kan ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo sọ fún yín, ẹ̀mí ni, ìyè sì ni Ṣùgbọ́n àwọn kan wà nínú yín tí kò gbàgbọ́, nítorí Jésù mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá ẹni tí wọ́n jẹ́ tí kò gbàgbọ́, àti ẹni tí yóò fi òun hàn Ó sì wí pé, Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, kò sí ẹni tí ó lè tọ̀ mí wá, bí kò ṣe pé a fi fún un láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá Nítorí èyí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ padà sẹ́yìn, wọn kò sì báa rìn mọ́ Nítorí náà Jésù wí fún àwọn méjìlá pé, Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ lọ bí Nígbà náà ni Símónì Pétérù dá a lóhùn pé, Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa ó lọ Ìwọ ni ó ni ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun Àwa sì ti gbàgbọ́, a sì mọ̀ pé ìwọ ni Kristì náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè Jésù dá wọn lóhùn pé, Ẹ̀yin méjìlá kọ́ ni mo yàn, ọ̀kan nínú yín kò ha sì ya Èṣù Jésù Lọ Sí Àjọ Ìpàgọ́ Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Jésù ńrìn ní Gálílì nítorí tí kò fẹ́ẹ́ rìn ní Jùdéà, nítorí àwọn Júù ń wá a láti pa Àjọ àwọn Júù tí í ṣe àjọ àgọ́ súnmọ́ etílé tan Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, Lọ kúrò níhín-ínyìí, kí o sì lọ sí Jùdéà, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pẹ̀lú lè fí iṣẹ́ rẹ hàn fún aráyé Nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí í ṣe ohunkóhun níkọ̀kọ̀, tí òun tìkáarẹ̀ sì ń fẹ́ kí a mọ òun ní gbangba Bí ìwọ bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn fún aráyé Nítorí pé àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá kò tilẹ̀ gbàágbọ́ Nítorí náà ni Jésù wí fún wọn pé, Àkókò gan-an fún mi kò tí ì dé fún ẹ̀yin, gbogbo àkókò ni ó dára fún yín Ayé kò lè kórìíra yín ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú Ẹ̀yin ẹ gòkè lọ sí àjọ yìí èmi kì yóò tí ì gòkè lọ sí àjọ yìí nítorí tí àkókò mi kò ì tí ì dé Nígbà tí ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn tan, ó dúró ní Gálílì síbẹ̀ Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ gòkè lọ tan, nígbà náà ni òun sì gòkè lọ sí àjọ náà pẹ̀lú, kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n bí ẹni pé níkọ̀kọ̀ Nígbà náà ni àwọn Júù sì ń wá a kiri nígbà àjọ wí pé, Níbo ni ó wà Kíkùn púpọ̀ sì wà láàárin àwọn ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀ nítorí àwọn kan wí pé, Ènìyàn rere níí ṣe Àwọn mìíràn wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n òun ń tan ènìyàn jẹ ni Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù Nígbà tí àjọ dé àárin Jésù gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì ó sì ń kọ́ni Ẹnu sì ya àwọn Júù, wọ́n wí pé, Ọkùnrin yìí ti ṣe mọ ìwé, nígbà tí kò kọ́ ẹ̀kọ́ Jésù dáhùn, ó sì wí pé, Ẹ̀kọ́ mi kì í ṣe tèmi, bí kò ṣe ti ẹni tí ó rán mi Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bíí bá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi Ẹni tí ń sọ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, òun ni olóòótọ́, kò sì sí àìsòdodo nínú rẹ̀ Mósè kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́ Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, Ìwọ ní ẹ̀mí èsù Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ Jésù dáhùn ó sì wí fún wọn pé, Kìkì iṣẹ́ àmì kan ni mo ṣe, ẹnu sì ya gbogbo yín Síbẹ̀, nítorí pé Mósè fi ìkọlà fún yín nítorí náà ẹ sì ń kọ ènìyàn ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mósè, ẹ ha ti ṣe ń bínú sími, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ṣáṣá ní ọjọ́ ìsinmi Ẹ má ṣe ìdájọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa se ìdájọ́ òdodo Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jérúsálẹ́mù wí pé, Ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nkankan sí i Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, Èyí ni Kírísítì náà Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá ṣùgbọ́n nígbà tí Kírísítì bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá Nígbà náà ni Jésù kígbe ní Tẹ́mpìlì bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀ Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà àtimú un ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbàágbọ́, wọ́n sì wí pé, Nígbà tí Kírísítì náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ àmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ Àwọn Farisí gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ àwọn Farisí àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn onísẹ́ lọ láti mú un Nítorí náà Jésù wí fún wọn pé, Níwọ̀n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i Yóò ha lọ sí àárin àwọn Hélénì tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Hélenì bí Ọ̀rọ̀ kí ni èyí tí ó sọ yìí, ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jésù dúró, ó sì kígbe wí pé, Bí òrùgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé-mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà Àwọn mìíràn wí pé, Èyí ni Kírísítì náà Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, Kírísítì yóò ha ti Gálílì wá bí Ìwé-mímọ́ kò ha wí pé, Kírísítì yóò ti inú irú ọmọ Dáfídì wá, àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìlú tí Dáfídì ti wá Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàárin ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀ Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹ́ḿpìlì padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá Àwọn ẹ̀ṣọ́ dáhùn wí pé, Kò sí ẹni tí ó tí ì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yìí rí! Nítorí náà àwọn Farisí dá wọn lóhùn pé, A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bí Ǹjẹ́ nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisí ti gbà á gbọ́ bí Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn yìí, tí ko mọ òfin di ẹni ìfibú Nikodémù ẹni tí ó tọ Jésù wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé, Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, Ìwọ pẹ̀lú wá láti Gálílì bí Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Gálílì dìde Wọ́n sì lọ olúkúlùkù sí ilé rẹ̀ Ẹ̀rí Jésù Dájú Jésù sì lọ sí orí òkè Ólífì Ó sì tún padà wá sí tẹ́ḿpìlì ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú ní ṣíṣe panṣágà wọ́n sì mú un dúró láàrin Wọ́n sì wí fún un pé, Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà, Ǹjẹ́ nínú òfin, Mósè pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí Èyí ni wọ́n wí, láti dán á wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn Ṣùgbọ́n Jésù bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀ Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ̀, ó nà rọ́, ó sì wí fún wọn pé, Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀ Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn a sì fi Jésù nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàárin, níbi tí ó wà Jésù sì nà rọ́, ó sì wí fún un pé, Obìnrin yìí, àwọn dà Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi Ó wí pé, Kò sí ẹnìkan, Olúwa Jésù wí fún un pé, Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi má a lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́sẹ̀ mọ́ Jésù sì tún sọ fún wọn pé, Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè Nítorí náà àwọn Farisí wí fún un pé, Ìwọ ń jẹ́rí ara rẹ ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́ Jésù dáhùn ó sì wí fún wọn pé, Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rí mi Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, Níbo ni Baba rẹ wà Jésù dáhùn pé, Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jésù sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹ́ḿpìlì ẹnikẹ́ni kò sì mú un nítorí wákàtí rẹ̀ kò tíì dé Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín ibi tí èmi gbé ńlọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá Nítorí náà àwọn Júù wí pé, Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí Nítorí tí ó wí pé, Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ̀yin ti ìsàlẹ̀ wá èmi ti òkè wá ẹ̀yin jẹ́ ti ayé yìí èmi kì í ṣe ti ayé yìí Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú níńu ẹ̀ṣẹ̀ yín Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, Ta ni ìwọ jẹ́ Jésù sì wí fún un pé, Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín ṣùgbọ́n olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn Lẹ́yìn náà Jésù wí fún wọn pé, Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé ẹ̀mi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan nítorí tí èmi ń se ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́ Nítorí náà Jésù wí fún áwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, Bí ẹ bá tẹ̀ṣíwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yin mi nítòótọ́ Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira Wọ́n dá a lóhùn pé, Irú-Ọmọ Ábúráhámù ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé ìwọ ha ṣe wí pé, Ẹ ó di òmìnira Jésù dá wọn lóhùn pé, Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni Ẹrú kì í sìí gbé ilé títí láé ọmọ ní ń gbé ilé títí láé Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́ Mo mọ̀ pé irú-ọmọ Ábúráhámù ni ẹ̀yin jẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí àyè nínú yín Jésù sọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ara rẹ̀ Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba ni mo sọ ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń ṣe èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, Ábúráhámù ni baba wa! Jésù wí fún wọn pé, Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Ábúráhámù Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run Ábúráhámù kò ṣe èyí Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, A kò bí wa nípa panṣágà A ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run Jésù wí fún wọn pé, Ìbáṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi Èé ṣe tí èdè mi kò fi yé yín Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́ nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀ Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́ Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ Bí mo bá ń ṣo òtítọ́ èé ṣe tí ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run Àwọn Júù dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, Àwa kò wí nítòótọ́ pé, ará Samaríà ni ìwọ jẹ́, àti pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù Jésù sì dáhùn pé, Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù, ṣùgbọ́n èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ẹ̀yin kò sì bu ọlá fún mi Èmi kò wá ògo ara mi Ẹnìkan ń bẹ tí ó ń wá a tí yóò sì ṣe ìdájọ́ Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò rí ikú láéláé Àwọn Júù wí fún un pé, Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù Ábúráhámù kú, àti àwọn wòlíì ìwọ sì wí pé, Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé Ìwọ ha pọ̀ ju Ábúráhámù Baba wa lọ, ẹni tí ó kú Àwọn wòlíì sì kú tani ìwọ ń fi ara rẹ pè Jésù dáhùn wí pé, Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ ǹkan Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ Ábúráhámù baba yín yọ̀ láti rí ọjọ́ mi ó sì rí i, ó sì yọ̀ Nítorí náà, àwọn Júù wí fún un pé, Ọdún rẹ kò ì tó àádọ́ta, ìwọ sì ti rí Ábúráhámù Jésù sì wí fún wọn pé, Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kí Ábúráhámù tó wà, èmi nìyìí Nítorí náà wọ́n gbé òkúta láti sọ lù ú ṣùgbọ́n Jésù fi ara rẹ̀ pamọ́, ó sì jáde kúrò ní tẹ́ḿpílì Jésù La Ojú Ẹni Tí A Bí Ní Afọ́jú Bí ó sì ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí rẹ̀ wá Àwọn Ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, Olùkọ́, ta ní ó dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yìí tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú Jésù dáhùn pé, Kì í ṣe nítorí pé ọkùnrin yìí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀ ṣùgbọ́n kí a baà lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lara rẹ̀ Àwa ní láti ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi, níwọ̀n ìgbà tí ó ba ti jẹ́ ọ̀sán òru ń bọ̀ wá nígbà tí ẹnìkan kì yóò lè ṣe iṣẹ́ Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé Nígbà tí ó ti wí bẹ́ẹ̀ tan, ó tutọ́ sílẹ̀, ó sì fi itọ́ náà ṣe amọ̀, ó sì fi amọ̀ náà pa ojú afọ́jú náà Ó sì wí fún un pé, Lọ wẹ̀ nínú adágún Sílóámù! Nítorí náà ó gba ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó wẹ̀, ó sì dé, ó ń ríran Ǹjẹ́ àwọn aládúgbò àti àwọn tí ó rí i nígbà àtijọ́ pé alágbe ni ó jẹ́, wí pé, Ẹni tí ó ti ń jókòó ṣagbe kọ́ yìí Àwọn kan wí pé òun ni Àwọn elòmíràn wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, ó jọ ọ́ ni Ṣùgbọ́n òun wí pé, Èmi ni Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, Bá wo ni ojú rẹ ṣe là Ó dáhùn ó sì wí fún un pé, Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jésù ni ó ṣe amọ̀, ó sì fi kùn mí lójú, ó sì wí fún mi pé, Lọ sí adágún Sílóámù, kí o sì wẹ̀, èmi sì lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran Wọ́n sì wí fún un pé, Òun náà ha dà Ó sì wí pé, Èmi kò mọ̀ Wọ́n mú ẹni tí ojú rẹ̀ ti fọ́ rí wá sọ́dọ̀ àwọn Farisí Ọjọ́ ìsinmi ni ọjọ́ náà nígbà tí Jésù ṣe amọ̀, tí ó sì là á lójú Nítorí náà àwọn Farisí pẹ̀lú tún bi í léèrè, bí ó ti ṣe ríran Ọkùnrin náà fèsìì, Ó fi amọ̀ lé ojú mi, mo sì wẹ̀, báyìí mo sì ríran Nítorí náà àwọn kan nínú àwọn Farisí wí pé, Ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, nítorí tí kò pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ Àwọn ẹlòmíràn wí pé, Ọkùnrin tí í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò ha ti ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ àmì wọ̀nyí Ìyapa sì wà láàárin wọn Nítorí náà, wọ́n sì tún wí fún afọ́jú náà pé, Kí ni ìwọ wí nítorí rẹ̀, nítorí tí ó là ọ́ lójú Ó sì wí pé, Wòlíì ní í ṣe Nítorí náà àwọn Júù kò gbàgbọ́ nípa rẹ̀ pé ojú rẹ̀ ti fọ́ rí, àti pé ó sì tún ríran, títí wọ́n fi pe àwọn òbí ẹni tí a ti là lójú Wọ́n sì bi wọ́n léèrè wí pé, Ǹjẹ́ èyí ni ọmọ yín, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, a bí ní afọ́jú Báwo ni ó ṣe ríran nísinsin yìí Àwọn òbí rẹ̀ dá wọn lóhùn wí pé, Àwa mọ̀ pé ọmọ wa ni èyí, àti pé a bí i ní afọ́jú Ṣùgbọ́n bí ó tí ṣe ń ríran nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ẹni tí ó là á lójú, àwa kò mọ̀ ẹni tí ó ti dàgbà ni Òun ẹ bi í léèrè yóò wí fúnra rẹ̀ Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn òbí rẹ̀ sọ, nítorí tí wọ́n bẹ̀rù àwọn Júù nítorí àwọn Júù ti fohùn sọ̀kan pé bí ẹnìkan bá jẹ́wọ́ pé Kírísítì ni, wọn ó yọ ọ́ kúrò nínú Sínágọ́gù Nítorí èyí ni àwọn òbí rẹ̀ fi wí pé, Ẹni tí ó dàgbà ni Òun, ẹ bi í léèrè Nítorí náà, wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì wí fún un pé, Fi ògo fún Ọlọ́run àwa mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkùnrin yìí jẹ́ Nítorí náà, ó dáhùn ó sì wí pé, Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni, èmi kò mọ̀ Ohun kan ni mo mọ̀, pé mo tí fọ́jú rí, nísinsin yìí mo ríran Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé, Kí ni ó ṣe ọ́ Báwo ni ó ṣe là ọ́ lójú Ó dá wọn lóhùn wí pé, Èmi ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọ́ nítorí kínni, ẹ̀yin ṣe ń fẹ́ tún gbọ́ Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ ṣe ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bí Wọ́n sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì wí pé, Ìwọ ni ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ ṣùgbọ́n ọmọ-ẹ̀yìn Mósè ni àwa Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mósè sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti eleyìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, Ohun ìyanu sáà ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n Òun sáà ti là mí lójú Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀ Láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò ì tí ì gbọ́ pé ẹnìkan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí Ìbáṣepé ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kì bá tí lè ṣe ohunkóhun Sí èyí, wọ́n fèsì pé Láti ìbí ni o tì jíngírí nínú ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ ha fẹ́ kọ́ wa bí Wọ́n sì tì í sóde Jésù gbọ́ pé, wọ́n ti tì í sóde nígbà tí ó sì rí i, ó wí pe, Ìwọ gba Ọmọ Ọlọ́run, gbọ́ bí Òun sì dáhùn wí pé, Ta ni, Olúwa, kí èmi lè gbà á gbọ́ Jésù wí fún un pé, Ìwọ ti rí i, Òun náà sì ni ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí Ó sì wí pé, Olúwa, mo gbàgbọ́, ó sì wólẹ̀ fún un J ésù sì wí pé, Nítorí ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran àti kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú Nínú àwọn Farisí tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ ǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì wí fún un pé, Àwa pẹ̀lú fọ́jú bí Jésù wí fún wọn pé, Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fọ́jú, ẹ̀yin kì bá tí lẹ́ṣẹ̀ ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin wí pé, Àwa ríran, nítorí náà ẹ̀ṣẹ̀ yín wà síbẹ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbé Ayé Jóòbù Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Húsì, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jóòbù ọkùnrin náà sì ṣe olóòótọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú, A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin àgùntàn, àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún ìbákasíẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àjàgà ọdámàlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀ jù gbogbo àwọn ará ìlà òòrun lọ Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀ wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àṣè wọn pé yíká, ni Jóòbù ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn nítorí tí Jóòbù wí pé bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọkàn wọn Bẹ́ẹ̀ ní Jóòbù máa ń ṣe nígbà gbogbo Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú Olúwa , Sàtánì sì wá pẹ̀lú wọn Olúwa sì bi Sàtanì wí pé, Níbo ni ìwọ ti wá Nígbà náà ní Sàtanì dá Olúwa lóhùn wí pé, Ní ìlọ-siwá-sẹ́yìn lórí ilẹ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀ Olúwa sì sọ fún Sàtanì pé ìwọ ha kíyèsí Jóòbù ìránṣẹ́ mi, pé kò sí èkejì rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòótọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kóríra ìwà búburú Nígbà náà ni sátanì dá Olúwa lóhùn wí pé, Jóòbù ha bẹ̀rù Olúwa ní asán bí Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo Ìwọ bùṣí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ si ní ilẹ̀ Ǹjẹ́, nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ni bí kì yóò sì bọ́hùn ni ojú rẹ Olúwa sì dá Sàtanì lóhùn wí pé, Kíyèsí i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkára rẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn Bẹ́ẹ̀ ni Sàtanì jáde lọ kúrò níwájú Olúwa Ó sì di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, tí wọ́n mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin Onísẹ́ kan sì tọ Jóòbù wá wí pé Àwọn ọ̀dà-màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn Àwọn ará Sábà sì kọ lù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ pẹ̀lú, wọ́n ti fi idà ṣá àwọn ìránṣẹ́ pa, èmi nìkan ṣoṣo ní ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ Bí ó ti ń sọ ní ẹnu ẹnìkan dé pẹ̀lu tí ó sì wí pé, Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́ èmi níkàn ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, Àwọn ará Kádéà píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọ lù àwọn ìbákasíẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lupẹ̀lu wọ́n sì fi idà ṣá àwọn ìránṣẹ́ pa èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ! Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnikàn dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n Sì kíyèsí i, ẹfúfù ńlá ńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọ lu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọdọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ Nígbà náà ni Jóòbù dìde, ó sì fa aṣọ ìgunwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà wí pé Ní ìhòòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá, ni ìhòòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ síbẹ̀ Olúwa fi fún ni, Olúwa sì gbà á lọ, ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa Nínú gbogbo èyí Jóòbù kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́ Àròyé Jóòbù Tẹ̀ṣíwájú Agara ìwà ayé mi dá mi tán, èmi yóò tú àròyé mi sókè lọ́dọ̀ mi, èmi yóò máa sọ níní kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé má ṣe dámi lẹ́bi fi hàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fí ń bá mi jà Ó ha tọ́ tí ìwọ ì bá fi máa ni mí lára, tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tí ìwọ yóò fi máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búrurú Ojú rẹ ìha ṣe ojú ènìyàn bí Tàbí ìwọ a máa ríran bí ènìyàn ti í ríran Ọjọ́ rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn, ọdún rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn Tí ìwọ fi ń bèèrè àìṣedédé mi, tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú, kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ Ọwọ́ rẹ ni ó dámi, tí ó sì mọ mí pọ̀ yíkákiri síbẹ̀ ìwọ sì ńbà mí jẹ́ Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ tí ìwọ ti mọ mí bí amọ̀ ìwọ yóò ha sì tún mú mi lọ padà sí erùpẹ̀ Ìwọ kò ha ti tún mí dà jáde bí i wàrà, ìwọ kò sì múmí dípò bí i wàràǹkàsì Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran ara wọ̀ mí, ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojú rere, ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́ Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pamọ́ nínú rẹ èmi mọ̀ pé, èyí ń bẹ ní ọkàn rẹ Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́mi ìwọ kì yóò sì dárí àìṣedédé mi jìn Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi! Bí mo bá sì ṣe ẹni rere, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè Nítorí mo wà nínú ìtọ́jú púpọ̀, mo sì wo ìpọ́jú mi Bí mo bá gbé orí mi ga Ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìhún àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú Ìwọ sì tún sọ àwọn ẹlẹ́rìí rẹ sí mi di ọ̀tún, Ìwọ sì sọ ìrúnú rẹ di púpọ̀ sí mi Àyípadà àti ogun dó tì mí Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá Áà! èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi Tí ó bá lejẹ́ pé èmi le wà láàyè, À bá ti gbé mi láti inú lọ isà-òkú Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí Rárá dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan Kí èmi kí ó tó lọ síbi tí èmi kì yóò padà sẹ́yìn mọ́, Àní kí ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú, Ilẹ̀ òkùnkùn bí òkùnkùn tìkárarẹ̀, Àti ti òjìji ikú, láìní ìtọ́, Níbi tí ìmọ́lẹ̀ dàbí òkùnkùn Sófárì Fi Ẹ̀sùn Irọ́ Pípa Àti Àìṣòótọ́ Kan Jóòbù Ígbà náà ni Sófárì, ará Naamáa, dáhùn, ó sì wí pé A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre Ṣé àmọ̀tàn rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni Ìwọ sáà ti wí fún Ọlọ́run pé, ìṣe mi jẹ́ aláìléérí, èmi sì mọ́ ní óju rẹ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀, kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ lára Kí ó sì fi àsírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ Nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olodùmáarè dé bi Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ kí ni ìwọ le è ṣe Ó jìn ju jíjìn isà òkú lọ kí ni ìwọ le mọ̀ Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ, ó sì ní ibú ju òkun lọ Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sénà, tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdajọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́ Òun sáà mọ ènìyàn asán àti pé ṣé bí òun bá rí ohun búburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn yóò di ọlọgbọ́n, nígbà tí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá bí ènìyàn Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un, tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, Bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù, tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ Nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láì ní àbàwọ́n, àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù, Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ, ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti ṣàn kọjá lọ Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ, bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísisinyìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀ Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́, àní ènìyàn yóò máa wá ojú rere rẹ Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n, ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ Ìdáhùn Jóòbù Jóòbù sì dáhùn, ó sì wí pé Kò sí àní-àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà, ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín! Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin èmi kò rẹ̀yìn sí i yín àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn à ń fi olóòótọ́ ẹni-ìdúró-ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà Ẹ̀gàn ni ẹni-ò-tòsì, tí ẹsẹ̀ rẹ múra tan láti yọ, nínú ìró ẹni tí ara rọ̀ Àgọ́ àwọn ìgárá ń bẹ̀rù àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu, àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn Ṣùgbọ́n nísínyìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ Tàbí ba ilẹ̀ àyé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ, àwọn ẹja inú òkun yóò sì sọ fún ọ Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí pé, ọwọ́ Olúwa ni ó ṣe nǹkan yìí Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo gbé wà, Àti ẹ̀mí gbogbo aráyé Etí kì í dán ọ̀rọ̀ wò bí, Tàbí adùn ẹnu kì í sì í tọ́ oúnjẹ rẹ̀ wò bí Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún, Àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye Pẹ̀lú rẹ Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára Òun ni ìmọ̀ àti òye Kíyèsí i, ó bì wó, a kò sì lè gbe ró mọ́ Ó ṣé ènìyàn mọ́, kò sì sí ìsísílẹ̀ kan Kíyèsí i, ó dá àwọn omi dúró, wọ́n sì gbẹ Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì sẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo Pẹ̀lú rẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun Ẹni tí ń sìnà àti ẹni tí ń mú ni sìnà, tirẹ̀ ni wọ́n ń ṣe Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòòhò, A sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀ Ó tú ìdè ọba, Ó sì fi mú àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòòhò, Ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò, Ó sì ra àwọn àgbààgbà ní iyè Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́là, Ó sì tú àmùrè àwọn alágbára Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá, Ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀ Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n Òun a sọ orílẹ̀-èdè di ńlá, a sì tún ṣẹ̀ wọn kù Òun a gba àyà olú àwọn ènìyàn aráyé, A sì máa mú wọn wọ́ kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí Wọn a máa fi ọwọ́ ta ilẹ̀ nínú òkùnkùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀, Òun a sì máa mú wọn tàsé ìrìn bí ọ̀mùtí Jóòbù Gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Ò ó, ojú mi ti rí gbogbo èyí rí, Etí mí sì gbọ́, ó sì ti yé e Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú, èmi kò rẹ̀yìn sí yin Nítòótọ́ èmi ó bá Olódumárè sọ̀rọ̀, Èmi sì ń fẹ́ bá Ọlọ́run sọ àsọyé Èyin ni oníhùmọ̀ èké, oníṣègùn lásán ni gbogbo yín Áà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́! Èyi ni kì bá sì ṣe ọgbọ́n yín Ẹ gbọ́ àwíyé mi nísinsìn yìí, Ẹ sì fetísilẹ̀ sí àròyé ètè mi Èyin fẹ́ sọ ìsọkúsọ fún Ọlọ́run Ki ẹ sì fi ẹ̀tàn sọ̀rọ̀ gbè é Ẹ̀yin fẹ́ ṣojúṣaajú rẹ̀ Ẹ̀yin fẹ́ gbèjà fún Ọlọ́run Ó ha dára tí yóò fi húdìí yín sílẹ̀, Tàbí kí ẹ̀yin tàn án bí ẹnìkan ti ítan ẹnìkejì Yóò máa bá yín wí nítòótọ́, Bí ẹ̀yin bá ṣojúusájú ènìyàn níkọ̀kọ̀ Ìwà ọlá rẹ̀ kì yóò bà yín lẹ́rù bí Ìpayà rẹ̀ kì yóò pá yín láyà Ìrántí yín dàbí eérú Ìlú odi yín ìlú odi amọ̀ Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi, kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀, ohun tí ń bọ̀ wá íbá mi, kí ó máa bọ̀ Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi èyín mi bu ẹran ara mi jẹ, Tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́ Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e Ṣùgbọ́n èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀ Èyí ni yóò sì ṣe ìgbàlà mi, Àgàbàgebè kì yóò wá síwájú rẹ̀ Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi ní ìfàyà balẹ̀, àti àṣọpé mí ni etí yín Wò ó nísinsin yìí, èmi ti làdí ọ̀ran mi sílẹ̀ èmi mọ̀ pé a ó dá mi láre Ta ni òun ti yóò bá mi ṣàròyé Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, èmi fẹ́ pa ẹnu mí mọ́, èmi ó sì jọ́wọ́ ẹ̀mi mi lọ́wọ́ Ṣùgbọ́n, má ṣe ṣe ohun méjì yìí sí mi, Nígbà náà ni èmi kì yóò sì fi ara mi pamọ́ kúrò fún ọ Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn kurò lára mi, má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kí ó pá mi láyà Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó pè, èmi o sì dáhùn Ta ni jẹ́ kí ń máa sọ̀rọ̀, ki ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn Mélòó ní àìṣedédé àti ẹ̀ṣẹ̀ mi Mú mi mọ̀ ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ mi Nítorí kí ni ìwọ ṣe pa ojú rẹ mọ́, tí o sì yàn mí ní ọ̀tá rẹ Ìwọ ó fa ewé ya ti afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún Ìwọ a sì máa lépa àkémọ́lẹ̀ pòròpórò gbígbẹ Nítorí pé ìwọ kọ̀wé ohun kíkorò sí mi, o sì mú mi ní àìṣedéédéé èwe mi Ìwọ kàn àbà mọ́ mi lẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú, ìwọ sì ń wò ipa ọ̀nà ìrìn mi ní àwòfín Ìwọ sì ń fi ìlà yí gìgisẹ̀ mi ká Àní, yí ẹni tí á ti run ká, bí ohun tí ó bu, Bí aṣọ tí kòkòrò jẹ bàjẹ́ Jóòbù Tẹ̀ṣíwájú Nínú Àròyé Rẹ̀ Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀ Ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́ Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá Kò sí ẹnìkan! Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀, ìye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ Ìwọ ti pàlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀ Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún ṣọ, àti pé ẹ̀ka rẹ̀ titun kì yóò dá Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀ Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gboorùn omi, yóò sọ yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù Àní ènìyàn jọwọ́ ẹ̀mi rẹ̀ lọ́wọ́ Òun ha dà Bí omi tí i sàn nínú ipa odò, tí odò sì ífà tí sì ígbẹ, bẹ́ẹ̀ ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́ títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́, wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn Áà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú, kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀, títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá, ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi! Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀ fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìwọ ń káye ìsísẹ̀ mi ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò, ìwọ sì rán àìṣedédé mi pọ̀ Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán, a sì sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀ Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì mú omi ṣàn bo ohun tí ó hù jáde lóri ilẹ̀, ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ Ìwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀ wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsìí lára wọn Ṣùgbọ́n ẹran ara rẹ̀ ni yóò rí ìrora Ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀ Élífásì Tako Ọ̀rọ̀ Jóòbù Ígbà náà ní Élífásì, ará Témà, dáhùn wí pé Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán, kí ó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà oòrun kún ara rẹ̀ nínú Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò ní èrè, tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere Ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì, ìwọ sì dí àdúrà lọ́nà níwájú Ọlọ́run Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí tì ọ́ Ìwọ ha íse ọkùnrin tí a kọ́ bi Tabì a há dá ọ ṣáájú àwọn òkè Ìwọ gburòó àsírí Ọlọ́run rí, tàbí ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀ Òye kí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa Eléwú ogbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa, tí wọ́n gbójú baba rẹ lọ Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ Èéṣe ti àyà rẹ fi ń dà ọ kiri, kí ni n mú ojú rẹ se wàìwàì Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run, tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀ Kí ni ènìyàn tí ó fi mọ́ Àti ẹni tí a tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo Kíyèsí i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀ Ańbọ̀tórí ènìyàn, ẹni ìríra àti eléèérìí, tí ń mù ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mú omi Èmi ó fihàn ọ́ gbọ́ ti èmi Èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ, tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn lati ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́, Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan, àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá, pẹ̀lú ìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo, àti iye ọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀ nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i O kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrò nínú òkùnkùn a sì ṣà á sápákan fún idà Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé, níbo ní ó wà Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn súnmọ́ tòsí Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú un bẹ̀rù, wọ́n ó sì sẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ímúra ogun Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdì sí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmáarè, Ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn giga, àní fi ìké kòóko àpáta rẹ̀ tí ó nipọn kọlù ú Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀ lojú, o sì ṣe jabajaba ọ̀rá sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ Òun sì gbé inú ahoro ìlú ìtakété, àti nínú iléyílé tí ènìyàn kò gbé mọ́, tí ó múra tán lati di àlàpà Òun kò lé ìlà, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kò lè dúró pẹ́ Bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀ Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn ọ̀wọ́ iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀, àti nípaṣẹ̀ ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ ní yóò máa kọjá lọ kúrò Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀le asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀ A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípẹ́ ọjọ́ rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù Yóò sì gbọ̀n àìpọ́n èṣo rẹ̀ dànù bí i àjàrà, yóò sì rẹ̀ ìyanna rẹ̀ nù bí i ti igi Ólífì Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebè yóò túká, iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀ Wọ́n lóyún ìwà ìkà, wọ́n sì bí ẹ̀ṣẹ̀, ikùn wọn sì pèṣè ẹ̀tàn Ìdáhùn Jóòbù Fún Élífásì Ígbà náà ní Jóòbù dáhùn, ó sì wí pé Èmi ti gbọ́ irú ohun pípọ̀ bẹ́ẹ̀ rí ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin Tàbí nín ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi, èmi le íkọ ọ̀rọ̀ pọ̀ si yin ni ọ̀run, èmi a sì mi orí mi sí i yín Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni ìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò tù bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí dé Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara Ìwọ mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété Ìwọ sì fi ìkiyẹ̀jẹ kùn mí lára, tí ó jẹ́rìí tì mí àti rírù tí ó yọ lára mi, ó jẹ́rìí lòdì sí ojú mi Ọlọ́run fi Ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì ṣọ̀tá mi ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi, ọ̀ta mi sì gbójú rẹ̀ sí mi Wọ́n ti fi ẹnu wọn yán sí mi Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn Wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já ó sì dì mí ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú, ó sì gbé mi kalẹ̀ ṣe àmì—ìtàfàsí rẹ̀ Àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi kákiri ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dásí, ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀ Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́ ó súré kọlù mi bí jagunjagun Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ n bò ara mi, mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀ Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún, òjìji ikú sì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi Kì í ṣe nítorí àìsòótọ́ kan ní ọwọ́ mi àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú Áà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi, kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan Ǹjẹ́ nísinsinyí kíyèsí i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run, ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín, ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run Ìbáṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run, bí ènìyàn kan ti íṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀ Nítorí nígbà tí iye ọdun díẹ̀ rékọjá tán, nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀ Ìdáhùn Jóòbù Ẹ̀mí mi bàjẹ́, ọjọ́ mi ni a ti gé kúrú, ìsà òkú dúró dè mí Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà h wà lọ́dọ̀ mi, ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn Ǹjẹ́ nísinsínyí, fi lélẹ̀ yàn onígbọ̀wọ́ fún mi lọ́dọ̀ rẹ ta ni Olúwa tí yóò le ṣe ààbò fún mi Nítorí pé ìwọ ti ṣé wọ́n láyà kúrò nínú òyè nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè Ẹni tí ó fi àwọn ọ̀rẹ́ hàn fún ìgárá, òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́, gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí, ẹni aláìsẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú, àti ọlọ́wọ́ mímì yóò máa lera síwájú Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín, ẹ yí padà, kí ẹ sì tún bọ̀ nísinsin yìí èmi kò le rí ọlọgbọ́n kan nínú yín Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìro mi ti fà já, àní ìro ọkàn mi Àwọn ènìyàn wọn yí ìsọ́ òru di ọ̀sán wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi mo ti tẹ́ ìbùsùn mi sínú òkùnkùn Èmi ti wí fún ìdibàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi, àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi, Ìrètí mi ha dà nísinsinyí Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú, nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ Ìdáhùn Bílídádì Ígbà náà ni Bílídádì, ará Ṣúà, dáhùn, ó sì wí pé Nígbà wo ni ẹ̀yin yóò tó fi ìdí ọ̀rọ̀ tì ẹ rò ó, nígbẹ̀yìn rẹ̀ ni àwa ó tó máa sọ Nítorí kí ni a ṣe ń kà wá sí bí ẹranko, tí a sì ń kà wá si bí ẹni ẹ̀gàn ní ojú yín Ìwọ fa ara rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú ìbínú rẹ̀ kí a ha kọ ayé sílẹ̀ nítorí rẹ̀ bi Tàbí kí a sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀ Nítòótọ́ ìmọ́lẹ̀ ènìyàn búburú ni a ó pa kúrò, Ọ̀wọ́ iná rẹ̀ kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn nínú àgọ́ rẹ̀, fìtílà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni a ó sì pa pẹ̀lú Ìrìn ẹṣẹ̀ agbára rẹ̀ yóò di fífọn ìmọ́lẹ̀ òun tìkárarẹ̀ ni yóò bí i ṣubú Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkararẹ̀ ó ti bọ́ sínú àwọ̀n, ó sì rìn lóri okùn dídẹ Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀, àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀ A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀, a sì wà ọ̀fìn fún un lojú ọ̀nà Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo, yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀ Àìlera rẹ̀ yóò di pipa fún ebi, ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀ àkọ́bí ikú ni yóò jẹ agbára rẹ̀ run A ó fà á tu kurò nínú àgọ́ tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ Yóò sì máa jókòó nínú àgọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe tirẹ̀ ìmí ọjọ́ ni a ó fún káàkiri ibùgbé rẹ̀ Gbòngbò rẹ̀ yóò gbẹ níṣàlẹ̀, a ó sì ké ẹ̀ka rẹ̀ kúrò lókè Ìrántí rẹ̀ yóò parun kúrò ni ayé, kì yóò sí orúkọ rẹ̀ ní ìgboro ìlú A ó sì lée láti inú ìmọ́lẹ̀ sí inú òkùnkùn, a ó sì lé e kúrò ní ayé Kì yóò ní ọmọ tàbí ọmọ ọmọ nínu àwọn ènìyàn rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò kù nínú agbo ilé rẹ̀ Ẹnu yóò ya àwọn ìran ti ìwọ̀ oòrùn sí ìgbà ọjọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù ìwárìrì ti í bá àwọn ìran ti ìlà oòrùn Nítòótọ́ irú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé àwọn ènìyàn búburú Èyí sì ni ipò ẹni tí kò mọ̀ Ọlọ́run Jóòbù Fún Bílídádì Ní Èsì Ígbà náà ni Jóòbù dáhùn, ó sì wí pé Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyà jẹ mí, tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ mi ní ìjàǹjá Ìgbà mẹ́wàá ní ẹ̀yin ti ń gàn mí ojú kò tìyín tí ẹ fi jẹ mí níyà Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo sìnà nítòótọ́, ìsìnà mi wà lára èmi tìkáarami Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́, tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú, Kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú, ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká Kiyè sì í, èmi ń kígbe pe, Ọwọ́ alágbára ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdajọ́ Ó sọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá, Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi Ó ti bọ́ ògo mi, ó sì sí adé kúrò ní orí mi Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo, ẹ̀mí sì pin ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi Ó sì tinábọ ìbínú rẹ̀ sími, ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀ Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi, wọ́n sì mọ odi yí mi ká, wọ́n sì yí àgọ́ mi ká Ó mú àwọn arákùnrin mi jìn nà sí mi réré, àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátapáta Àwọn alájọbí mi fà sẹ́yìn, àwọn afaramọ́ ọ̀rẹ́ mi sì di onígbàgbé mi Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́ Ẹ̀mí mi sú àyà mi, àti òòrun mi sú àwọn ọmọ inú ìyá mi Àní àwọn ọmọdé kùnrin fi mí ṣẹ̀sín Mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi, àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran ara mi, mo sì bọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi Ẹ ṣáànú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí Nitorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bí Ọlọ́run, tí ẹran ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn Áà! Ìbáṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ mi nísinsìn yìí, ìbáṣepé a le dà á sínú ìwé! Kí a fi kálàmú irin àti ti òjé kọ wọ́n sínú àpáta fún láéláé Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáùndè mi ń bẹ láàyè àti pe òun ni yóò dìde dúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn Àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ ara mi run, síbẹ̀ láìsí ẹran ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run, Ẹni tí èmi ó rí fún ara mi, tí ojú mi ó sì wo, kì sì íṣe ti ẹlòmìíràn ọkàn mi sì dákú ní inú mi Bí ẹ̀yin bá wí pé, àwa ó ti lépa rẹ̀ tó! Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a ṣáà rí ní ọwọ́ rẹ̀, Kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù nítorí ìbínú ní ímú ìjìyà wá nípa ìdà Kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ Ọlọ́run Gbà Fún Sàtánì Kí Ó Dán Jóòbù Wò Lẹ́ẹ̀kejì Ó sì tún di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá síwájú Olúwa , Sàtánì sì wá pẹ̀lú wọn láti pe níwájú Olúwa Olúwa sì bi Sàtánì pé, Níbo ni ìwọ ti wá Sàtánì sì dá Olúwa lóhùn pé, Láti lọ síwá sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀ Olúwa sì wí fún Sàtánì pé, Ìwọ ha kíyèsí Jóòbù ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí èkejì rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí ń ṣe olóòótọ́ tí ó sì dúró sinsin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kóríra ìwà búburú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìwà òtítọ́ rẹ̀ mu ṣinṣin, bí ìwọ tilẹ̀ ti dẹ mí sí i láti run-ún láìnídìí Sàtánì sì dá Olúwa lóhùn wí pé, Awọ fún awọ àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀ Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsìn yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ Olúwa sì wí fún Sàtánì pé, Wò ó, Ó ń bẹ ní ìkàwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni Sàtánì jáde lọ kúrò níwájú Olúwa , ó sì sọ Jóòbù ní oówo kíkan kíkan láti àtẹ́lẹṣẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń ha ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún-un pé, Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú! Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn obìnrin aláìmọ́ye ti í sọ̀rọ̀ há bà! Àwa yóò ha gba ire lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi Nínú gbogbo èyí, Jóòbù kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀ Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀ Élífásì, ara Témà àti Bílídádì, ara Ṣúà, àti Sófárì, ará Náámù nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a sọ̀fọ̀ àti láti sìpẹ̀ fún un Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún olúkúlùkù sì fa àṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jòkòó tì í ní inú erùpẹ̀ ní ọjọ́ méje ti ọ̀sán ti òru, ẹnikẹ́ni kò sì bá a dá ọ̀rọ̀ kan sọ nítorí tí wọ́n ti rí i pé ìbànújẹ́ rẹ̀ pọ̀ gidigidi Ìdáhùn Sófárì Ígbà náà ní Sófárì, ara Náámà dáhùn, ó sì wí pé Nítorí náà ní ìro inú mi dá mi lóhùn, àti nítorí èyí náà ní mo sì yára si gidigidi Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi, ẹ̀mí òye mi sì dá mi lóhùn Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́, láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ silẹ̀ ayé, Pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni, àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run, ti ori rẹ̀ sì kan àwọsánmà Ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀ àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, Òun ha dà Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i, àní a ó lé e lọ bi ìran òru Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́ Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojú-rere lọ́dọ̀ talákà, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀, tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀ Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnu rẹ̀, bí ó tilẹ̀ pa á mọ́ nísàlẹ̀ ahọ́n rẹ̀, bí ó tilẹ̀ dá a sí, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó pa á mọ́ síbẹ̀ ní ẹnu rẹ̀, Ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ ti yípadà, ó jásí òróró pamọ́lẹ̀ nínú rẹ̀ Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá Ó ti fà oró pamọ́lẹ̀ múu ahọ́n gúnte ní yóò pa á Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì, ìṣàn omi, odò tí ń sàn fún oyin àti ti òrí àmọ́ Ohun tí ó ṣíṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì yọ̀ nínú rẹ̀ Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni talákà lára, ó sì ti kẹ́hìndà wọ́n Nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́ Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀, kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkán rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀ Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀ Nitorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́ Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́ jọ lé e lórí Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun Ọlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí, nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́, yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí Yóò sá kúrò lọ́wọ́ ohun ogun ìrìn ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára idà dídán ní ń jáde láti inú òróòro wá Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀ Òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀ iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn, ayé yóò sì dìde dúró sí i Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ, àti ohun ìní rẹ̀ yóò ṣàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run Èyi ni ìpín ènìyàn buburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, àti ogún tí a yàn sílẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Jóòbù Dá Sófárì Lóhùn Jóòbù wá dahùn, ó sì wí pé Ẹ tẹ́tí silẹ̀ dẹdẹ sì àwọn ọ̀rẹ́ mi, kí èyí kí ó jásí ìtùnú tí ó fún mi Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìgbà tí mo bá sọ tán, ìwọ máa fi ṣẹ̀sín ń ṣo Bí ó ṣe tí èmi ni, àròyé mi iṣe sí ènìyàn bí Tàbí èétíṣe tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀ Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín, kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí, ìwárìrì sì mú mi lára Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà ní ayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa Irú ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojú wọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ-ọmọ wọn ní ojú wọn Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá iná Ọlọ́run kò sí lára wọn Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì ísì íṣe abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn wẹ́ẹ́wẹ́ẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jó kiri Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti háápù, wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè Wọ́n ní ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀ wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, lọ kúrò lọ́dọ̀ wa, nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ! Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i Kíyè sí i, àlàáfíà wọn kò sí nípa ọwọ́ wọn ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí ni réré Ìgbà mélòómélòó ní a ń pa iná ènìyàn búburú kú Ìgbà mélòómélòó ní ìparun wọn dé bá wọn, tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀ Wọ́n dàbí àkékù oko níwájú afẹ́fẹ́, àti bí ìyàngbò, tí ẹfúùfù ńlá fẹ́ lọ Ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run to iya ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀, yóò sì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì Ẹnikẹ́ni le íkọ́ Ọlọ́run ní ìmọ̀ Òun ní í sáa ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga Ẹnìkan a kú nínu pípé agbára rẹ̀, ó wà nínú ìrọra àti ìdákẹ́ pátapáta Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú, egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá Ẹlòmìíràn a sì kú ninú kíkorò ọkàn rẹ̀, tí kò sì fi inú dídùn jẹun Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀, kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n Kíyèsí i, èmi mọ̀ ìrò inú yín àti àrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, Níbo ní ilé ọmọ aládé, àti níbo ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà Ẹ̀yin kò mọ̀ àmì wọn, pé Ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú Ta ni yóò sọ ipa ọ̀nà rẹ̀ kò ó ní ojú, ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú, a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú Ògúlùtù àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, bí ènìyàn àìníye ti lọ ṣíwájú rẹ̀ Èé ha ti ṣe tí ẹ̀yin fi ń tù mí nínú lásán, bí ò ṣepé ní ìdáhùn yín, eké kù níbẹ̀! Èsì Élífásásì Ígbà náà ni Élífásì, ará Témà, dáhùn wí pé Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run Bí ọlọ́gbọ́n ti í ṣe rere fún ara rẹ̀ Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmáarè pé, olódodo ni ìwọ Tàbí èrè kí ni fún un, ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi, àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láìníye Nítòótọ́ ìwọ bèèrè fún ààbò ni ọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí, ìwọ sì tú oníhòhò ní aṣọ wọn Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu, ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa Bí ó ṣe ti alágbára nì ni, òun ni ó ní ilẹ̀, ọlọ́lá sì tẹ̀dó sínú rẹ̀ Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ ní ọwọ́ òfo Apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́ Nítorí náà ni ìdẹkùn ṣe yí ọ káàkiri, àti ìbẹ̀rù òjijì ń yọ ọ́ lẹ́nu, Èé ṣe tí òkùnkùn, fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè ríran Èé ṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀ Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run Ṣá wò orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó! Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀ Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí Àwọ̀sánmọ̀ tí ó nípọn ni ìbora fún un, tí kò fi lè ríran ó sì rìn nínú àyíká ọ̀run Ìwọ fẹ́ rìn ìpa ọ̀nà ìgbàanì tí àwọn ènìyàn búburú tí rìn A ké wọn lulẹ̀ kúrò nínú ayé láìpé ọjọ́ wọn ìpilẹ̀ wọn ti dé bí odò síṣàn Àwọn ẹni tí ó wí fún Ọlọ́run pé, lọ kúrò lọ́dọ̀ wa! Kí ni Olódùmárè yóò ṣe fún wọn Ṣíbẹ̀ ó fi ohun rere kún ilé wọn! Ṣùgbọ́n ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi! Àwọn olódodo rí ìparun wọn, wọ́n sì yọ̀, àwọn aláìlẹ̀ṣẹ̀ sì fi wọ́n rẹ́rìn ín ẹlẹ́yà pé, Lótìítọ́ àwọn ọ̀ta wa ni a ké kúrò, iná yóò sì jó oró wọn run Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà Pẹ̀lú rẹ̀ nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá, kí o sì tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmáarè, a sì gbé ọ ró, bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ, Tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀ lórí erùpẹ̀ àti wúrà ófiri lábẹ́ òkúta odò, Nígbà náà ní Olódùmáarè yóò jẹ́ wúrà rẹ, àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ Lótìítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmáarè, ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ, ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ Nígbà tí ipa-ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀, nígbà náà ni ìwọ o wí pé, Ìgbésókè ń bẹ! Ọlọ́run yóò sì gba onírẹ̀lẹ̀ là! Yóò gba ẹni tí kì í iṣe aláìjẹ̀bi là, a ó sì gbà á nípa mímọ́ ọwọ́ rẹ̀ Èsì Jóòbù Ígbà náà ni Jóòbù sì dáhùn wí pé Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò ọwọ́ mí sì wúwo sí ìkérora mi Áà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀! Èmi ibá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀, ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá mi lóhùn òye ohun tí ìbá wí a sì yé mi Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsí mi Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́, níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ onídájọ́ mi láéláé Sì wòó, bí èmi bá lọ sí iwájú, òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀ Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i, ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apa ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀, nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà Ẹṣẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipaṣẹ̀ ìrìn rẹ̀ ọ̀nà rẹ̀ ni mo ti kíyèsí, tí ń kò sì yà kúrò Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹ̀nu rẹ̀, èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀ nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà, Olodùmáarè sì ń dààmú mi, Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi Ìbéèrè Jóòbù Se bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmárè fún ìdájọ́, èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀ Díẹ̀ nínú wọn a ṣún àmì ààlà ilẹ̀, wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n sì ji wọn Wọ́n á sì dà kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba lọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá-màlúù opó ní ohun ògo Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà, àwọn talákà àyé a sá pamọ́ pọ̀ Kíyèsí i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ nínú ijù ni àwọn talákà ijáde lọ sí iṣẹ́ wọn Wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn Olúkulùkù a sì ṣa ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko, wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú Ní hòòhò ni wọn má a sùn láìní aṣọ, tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù Ọ̀wàrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n, wọ́n sì lẹ̀mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú, wọ́n sì gbà ọmọ talákà Nítorí gbèsè Wọ́n rìn kiri níhòòhò láìní aṣọ àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà, Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínú àgbàlá wọn, tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntí àjàrà, òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá, ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́ ṣíbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsí àṣìṣe náà Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó kọ̀ ìmọ́lẹ̀ Wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀ Panipani a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, a sì pa talákà àti aláìní, àti ní òru a di olè Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró de àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀ Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé, tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán, wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀ Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn Ó yára lọ bí ẹni lójú omi ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun òun kò rìn mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà Ọ̀dá àti òru ní ímú omi ojọ-didi gbẹ, bẹ́ẹ̀ ní isà òkú írun àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀, kòkòrò ní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀, a kì yóò rántí ènìyàn búburú mọ́ Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn tí kò ṣe rere sí opó Ṣùgbọ́n ó fi ipá Ọlọ́run rẹ̀ fà alágbára lọ pẹ̀lú Ó dìde, kò sí ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀ dá lójú Ọlọ́run sì fi ìwà àìléwu fún un, àti nínú èyí ní a ó sì tì i lẹ́yìn, ojú rẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn A gbé wọn lékè nígbà díẹ̀ wọ́n kọjá lọ, a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ A sì mú wọn kúrò ní ọ̀nà, bí àwọn ẹlòmìíràn, a sì ké wọn kúrò bí orí sírì itú ọkà bàbà Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsìn yìí, ta ni yóò mú mi ní èké, tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí Ìdáhùn Bílídádì Ígbà náà ní Bílídádì, ará Ṣúà, dáhùn wí pé Ìjọba àti ẹ̀ru ḿbẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀, òun ní iṣe ìlàjà ní ibi gígagíga ọ̀run Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí, tàbí ara tani ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí Èé ha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́ Kíyèsí i, òṣùpá kò sì lè í tàn ìmọ́lẹ̀, àní àwọn ìràwọ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀ Áḿbọ̀torí ènìyàn tí iṣe ìdin, àti ọmọ ènìyàn tí iṣe kòkòrò! Ìdáhùn Jóòbù Ṣùgbọ́n Jóòbù sì dáhùn wí pé Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá, báwo ní ìwọ ń ṣe gbà apá ẹni tí kò ní agbára Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ ẹni tí kò ní ọgbọ́n, tàbí báwo ní ìwọ sọdi ọ̀ràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí ó ti rí Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti ẹ̀mi ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀ Àwọn aláìlágbára ti iṣà òkú wárìrì, lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ Ìhòòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run, ibi ìparun kò sí ní ibojì Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfùrufú, ó sì fi ayé rọ̀ ní ojú òfo Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkù àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn, ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí Ó fi idẹ yí omi òkun ká, títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn Ọ̀wọ̀n òpó ọ̀run wárìrì, ẹnu sì yà wọ́n sì ìbàwí rẹ̀ Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi òkun nípa òye rẹ̀, ó gé Ráhábù sí wẹ́ẹ́wẹ́ Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀sọ́ ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti dá ejò wíwo nì Kíyèsí i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀ ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó! Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé Pẹ̀lúpẹ̀lú Jóòbù sì tún sọ kún ọ̀rọ̀ òwe rẹ̀, ó sì wí pé Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ìdájọ́ mi lọ, àti Olódùmárè tí ó bà mi ní ọkàn jẹ́ Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ èké, Bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n mi kì yóò sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn Kí a má ríi pé èmi ń dá yín láre títí èmi ó fi kú, èmi kì yóò sí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi Òdodo mi ni èmi dìmú ṣinṣin, èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ àyà mi kì yóò sì gan ọjọ́ kan nínú ọjọ́ ayé mi Kí ọ̀ta mi kí ó dàbí ènìyàn búburú, àti ẹni tí ń dìde sími kí ó dàbí ẹni aláìsòdodo Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè, nígbà tí Ọlọ́run bá ké ẹ̀mí rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì fà á jáde Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀, nígbà tí ìpọ́jú bá dé sí i Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè Òun ha lé máa képe Ọlọ́run nígbà gbogbo Èmi ó kọ́ yín ní ẹ̀kọ́ ní ti ọwọ́ Ọlọ́run ọ̀nà tí ńbẹ lọ́dọ̀ Olódùmarè ni èmi kì yóò fi pamọ́ Kíyèsí i, gbogbo yín ni ó ti rí i nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe já sí asán pọ̀ bẹ́ẹ̀ Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti ogún àwọn aninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmáre Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fún idà ni àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ Àwọn tí ó kú nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-àrùn àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sunkún fún wọn Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀, tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀ Àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòótọ́ ni yóò lò ó àwọn aláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀ Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ, àti bí ahéré tí olùsọ́ kọ́ Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kì yóò tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ ó síjú rẹ̀, òun kò sì sí Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo rẹ̀ a lọ Ẹ̀rù ńlá bàá bí omi ṣíṣàn ẹ̀fúùfù ńlá jí i gbé lọ ní òru Ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn gbé e lọ, òun sì lọ àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀ Nítorí pé Olódùmárè yóò kọ lù ú, kì yóò sì dá a sí òun ìbá yọ̀ láti sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí i lórí, wọn yóò sì ṣe síọ̀ sí i kúrò ní ipò rẹ̀ Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àti òye Jóòbù Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ, àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin, bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá Ènìyàn ni ó parí òkùnkùn, ó sì ṣe àwárí òkúta òkùnkùn àti ti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jìn sí àwọn tí ń gbé òkè, àwọn tí ẹṣẹ̀ ènìyàn gbàgbé wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀, wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá, àti ohun tí ó wà ní ìṣàlẹ̀ ni ó yí sókè bí ẹni pé iná Òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta Sáfírì, o sì ní erùpẹ̀ wúrà Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀, àti ojú gúnnugún kò rí i rí Àwọn ẹrankan agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta, ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta, ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún —kún-ya, ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀ Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè Ọ̀gbun wí pé, kò sí nínú mi omi òkun sì wí pé, kò si nínú mi A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùnwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀ A kò le è fi wúrà Ófírì, tàbí òkútà Óníkísì iyebíye, tàbí òkúta Sáfírì díye lé e Góòlù àti òkúta Kírísítalì kò tó ẹgbẹ́rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èló wúrà ṣe pàsípààrọ̀ rẹ̀ A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta Jásípérì iye ọgbọ́n sì ju òkúta Rubì lọ Òkùta tópásì ti Kúsì kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀ Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá Tàbí níbo ni òye ń gbé A rí i pé, ó farasinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo, ó sì fara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run Ibi ìparun àti ikú wí pé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀ Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run, Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fi òṣùwọ̀n wọ̀n omi Nígbà tí ó pàsẹ fún òjò, tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá, Nígbà náà ni órí i, ó sì sọ ọ́ jáde ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí Àti fún ènìyàn ni ó wí pé, Kíyè sí i ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n, àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye   Jóòbù Rántí Ìbùkún Rẹ̀ Àtẹ̀yìnwá Pẹ̀lúpẹ̀lù, Jóòbù sì tún tẹ̀ ṣíwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé Áà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tí ó kọjá, bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pamímọ́ Nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí, àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já Bí mo tirí nígbà ọ̀dọ́ mi, nígbà tí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi Nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi, nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká Nígbà tí èmi fi òrí àmọ́ n wẹ ìsísẹ̀ mi, àti tí àpata ń tú ìsàn òróró jáde fún mi wá Nígbà tí mo jáde la àárin ìlú lọ sí ẹnu ibodè, nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro, Nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rí mi, wọ́n sì sápamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹṣẹ̀ wọn Àwọn ọmọ aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sí sọ, wọn a sì fí ọwọ́ wọn lé ẹnu Àwọn ọmọ ọlọ́lá dákẹ́, ahọ́n wọn sì lẹ̀mọ́ èrìgì ẹnu wọn Nígbà tí etí gbọ́, ó sì súre fún mi, àti nígbà tí ojú sì rí mi, ó jẹ́rìí mi Nítorí mo gbà talákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́, àti aláìní baba, tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi, èmi sì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀ Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ, ẹ̀tọ́ mi dà bí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹṣẹ̀ fún amúkùnún Mo ṣe baba fún talákà, mo ṣe ìwádìí ọ̀ràn àjòjì tí èmi kò mọ̀ rí Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ìkà ènìyàn, mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀ Nígbà náà ni mo rò pé, Èmi yóò kú nínú ilé mi, èmi yóò sì mú ọjọ́ mi pọ̀ sí i bí i yanrìn Gbòǹgbò mi yóò ta kan omi, ìrì yóò sì sẹ̀ ní gbogbo òru sí ara ẹ̀ka mi Ògo mi yóò wà ní ọ̀tún ní ọ̀dọ̀ mi, ọrun mi sì padà di titun ní ọwọ́ mi Èmi ni ènìyàn ń dẹtí sílẹ̀ sí, wọn a sì dúró, wọn a sì dákẹ́ rọ́rọ́ ní ìmọ̀ràn mi Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ mi, wọn kò tún sọ̀rọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ mi wọ̀ wọ́n ní etí ṣinṣin Wọn a sì dúró dè mí bí ẹni wí pé wọ́n dúró fún ọ̀wọ́ òjò wọn a sì mu nínú ọ̀rọ̀ mi bí ẹní mu nínú òjò àrọ̀-kúrò Èmi sì rẹ́rìn ín sí wọn nígbà tí wọn kò bá gbà á gbọ́ ìmọ́lẹ̀ ojú mi jẹ́ iyebíye síwọn Mo la ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn, mo sì jókòó bí olóyè wọn mo jókòó bí ọba ní àárin ológun rẹ̀ mo sì rí bí ẹni tí ń tu ẹni tí ń sọ̀fọ̀ nínú Jóòbù Fi Ọjọ́ Ibí Rẹ̀ Ré Ẹ̀yìn èyí ní Jóòbù yanu, ó sì fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré Jóòbù sọ, ó sì wí pé Kí ọjọ́ tí a bi mi kí ó di ìgbàgbé, àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, A loyún ọmọkùnrin kan! Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn, kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i Kí òkùnkùn àti òjìjì ikú fi ṣe ti ara wọn kí àwọ-sánmọ̀ kí ó bà lé e kí ìṣúdúdú ọjọ́ kí ó pa láyà Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri, kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà kí ó má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù Kí òru náà kí ó yàgàn kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn-ún kí o fi gégùn-ún, tí wọ́n mura tán láti ru Léfíátánì sókè Kí ìràwọ̀ òféfé ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ síi, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀rẹ̀mọ́jú mọ́ Nítorí tí kò sé ìlẹ̀kùn inú ìyá mi, bẹ́ẹ̀ ni kò pa ìbànújẹ́ rẹ́ ní ojú mi Èéṣe tí èmi kò fi kú láti inú wá, tàbí tí èmi kò fi pín ẹ̀mí ní ìgbà tí mo ti inú jáde wá Èéṣe tí eékún wá pàdé mi, tàbí ọmú tí èmi yóò mu Ǹjẹ́ nísinsìn yìí èmi ìbá ti dúbúlẹ̀ jẹ́ẹ́ èmi a sì dákẹ́, èmi ìbá ti sùn ǹjẹ́ èmi ìbá ti sinmi pẹ̀lú àwọn ọba àti ìgbìmọ̀ ayé tí ìmọ́lẹ̀ takété fún ara wọn Tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé tí ó ní wúrà, tí wọ́n sì fi fàdákà kun ilé wọn Tàbí bí ọ̀lẹ̀ tí a sin, èmi kì bá ti sí bí ọmọ ìṣúnú tí kò rí ìmọ́lẹ̀ Níbẹ̀ ni ẹni-búburú síwọ́ ìyọ nilẹ́nu, níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀, wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́ Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀, ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀ Nítorí kí ni a ṣe fi ìmọ́lẹ̀ fún òtòsì, àti ìyè fún ọlọ́kan kíkorò, tí wọ́n dúró de ikú, ṣùgbọ́n òun kò wá, tí wọ́n wálẹ̀ wá a jù fún ìṣúra tí a bò mọ́lẹ̀ pamọ́ Ẹni tí ó yọ̀ gidigidi, tí inú wọ́n sì dùn nígbà tí wọ́n wá ibojì òkú rí Kí ni a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ fi ara pamọ́ fún tí Ọlọ́run sì ṣọgbà yí wọn ká Nítorí pé èémí-ẹ̀dùn wà ṣáájú oúnjẹ mi ikérora mi sì tú jáde bí omi Nítorí pé ohun náà tí mo bẹ̀rù gidigidi ni ó dé bá mi yìí, àti ohun tí mo fòyà rẹ̀ bá mi ó sì ṣubú lù mí Èmi kò wà ni ìléwu rí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ní ìsinmi bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ni ìfàyà balẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ ìyọnu dé Ọ̀rọ̀ Ìbànújẹ Jóòbù Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, baba ẹni tí èmi kẹ́gàn láti tò pẹ̀lú àwọn ajá agbo-ẹran mi Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sími, níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀ Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ ní ibi ìkọsílẹ̀ ní òru Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá ìgbẹ́ gbogbo igikígi ni ounjẹ jíjẹ wọn A lé wọn kúrò láàrin ènìyàn, àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkùta àfonífojì, nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta Wọ́n ń dún bí ẹranko ní àárin ìgbẹ́, wọ́n kó ara wọn jọpọ̀ ní abẹ́ èṣìsì Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé, àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀ Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin àní èmi di ẹni ìsọ̀rọ̀ sí láàrin wọn Wọ́n kórìíra mi wọ́n sá kúrò jìnnà sími, wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sími lójú Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìjánu níwájú mi Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò, wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dèmí Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀, àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ Wọ́n ya sími bí i omi tí ó ya gbuuru ní ariwo ńlá ni wọ́n kó ara wọn ká tì sí mi Ẹ̀rù ńlá bà mí wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù, àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀ Àti nísinsin yìí ọkàn mí sì dà jáde síi ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mí mú Òru gún mi nínú egungun mi, ìyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi, ó sì lẹ̀mọ́ mi ní ara yíká bí ọrùn aṣọ ìlekè mi Ọlọ́run ti mú mi lọ sínú ẹrẹ̀, èmi sì dàbí eruku àti eérú Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run ṣùgbọ́n, ìwọ kò dámi lóhùn èmi dìde dúró ìwọ sì wò mí lásán Ìwọ padà di ẹni ìkà sími ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ fi dè mí ní ọ̀nà Ìwọ gbémi sókè sí inú ẹ̀fúùfù, ìwọ múmi fò lọ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì sọ mí di asán pátapáta Èmi sáà mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú, sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha na ọwọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubu rẹ̀, tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀ Èmi kò ha sunkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún talákà bí Nígbà tí mo fojú sọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé Ikùn mí n ru kò sì sinmi Ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bámi Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú òòrùn èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbé fún ìrànlọ́wọ́ Èmi ti di arákùnrin ìkòokò, èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò Àwọ̀ mi di dúdú ó sì ń bọ́wọ̀ egungun mi sì jórun fún oru Hapu orin mi pẹ̀lú sì di ti ọ̀fọ̀, àti ìpè orin mi sì di ohùn àwọn tí ń sunkún Àwíjàre Jóòbù Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mu, èmi yó ha ṣe tẹjú mọ́ wúndíá Nítórí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá Tàbí kí ni ogún Olódùmárè láti òkè ọ̀run wá Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún, àti àjàkálẹ̀ àrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi, òun kò ha sì ka gbogbo ìṣíṣẹ̀ mi Bí ó bá ṣepé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn, tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn Bí ẹṣẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀mọ́ mi ní ọwọ́, Ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmìíràn kí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú ọmọ mi tu Bí àyà mi bá di fífà sípasẹ̀ obinrin kan, tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu ọ̀nà ilé aládùúgbò mi, Ṣùgbọ́n kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn, kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀ Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀ Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun, tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu Tí mo bá sì se àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí, nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà Kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú talákà, tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó di aláìríran, Tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ, tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀ Nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba, èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá Bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ, tàbí talákà kan láìní ìbora Bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi, tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípaṣẹ̀ irun àgùntàn mi Bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba, nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè, Ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ọkọ́ èjìká rẹ̀, kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù-ńlá fún mi, àti nitorí Ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi, tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, Ìwọ ni ààbò mi Bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀, àti nítorí ọwọ́ mi dẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ Bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn, tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀, Bí a bá tàn ọkàn mi jẹ Láti fí ẹnu mi kò ọwọ́ mi Èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn Onidàájọ́ ní bẹ̀wò Nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè Bí ó bá ṣepé mo yọ̀ sì ìparun ẹni tí ó korìíra mi Tàbí bí mo bá sì gbéra sókè, nígbà tí ibi bá a Bẹ́ẹ̀ èmí kò sì jẹ ẹnu mi ki ó ṣẹ̀ nípa fífi ègún sí ọkàn rẹ̀ Bí àwọn ènìyàn inú àgọ́ mi kò bá lè wí pé, ta ni kò ì tí ì jẹ ẹran rẹ̀ ní àjẹyó Bí mo bá bò ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ bí Ádámù, ni pápá, ẹ̀bi mi mọ́ ni àyà mi Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni mo ha bẹ̀rù bí Tàbí ẹ̀gan àwọn ìdílé ní ń bà mí ní ẹ̀rù Tí mo fi p'ẹnu mọ́, tí èmí kò sì fi jáde sóde Bí ilẹ̀ mi bá sì ké rara lòdì sí mi tí a sì fi omijé kún gbogbo poro rẹ̀ Bí mo bá jẹ èṣo oko mi láìsánwọ́ tàbi tí mo sì mú ọkàn olúwa rẹ̀ fò lọ, kí ẹ̀gún òṣùṣú kí ó hù dípò àlìkámà, àti èpò búburú dípò ọkà bárlè Ọ̀rọ̀ Jóòbù parí Ọ̀rọ̀ Élíhù Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí dákẹ́ láti dá Jóòbù lóhùn, nítorí ó ṣe olódodo lójú ara rẹ̀ Nígbà náà ni inú bí Élíhù ọmọ Bárákélì ará Búsì, láti ìbátan ìdílé Rámù ó bínú si Jóòbù nítorí ti ó dá ara rẹ̀ láre kàkà ki ó dá Ọlọ́run láre Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọn kò rí ọ̀nà láti dá Jóòbù lóhùn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá Jóòbù lẹ́bi Ǹjẹ́ Élihù ti dúró tití Jóòbù fi sọ̀rọ̀ tán nitorí tí àwọn wọ̀nyí dàgbà ju òun lọ ní iye ọjọ́ Nígbà tí Élíhù ríi pé ìdáhùn ọ̀rọ̀ kò sí ní ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí nígbà náà ni ó bínú Élíhù, ọmọ Bárákélì, ará Búsì, dáhùn ó sì wí pé ọmọdé ní èmi àgbà sì ní ẹ̀yin Ǹjẹ́ nítorí náà ní mo dúró mo sì ń bẹ̀rù láti fi ìmọ̀ mi hàn yin Èmi wí pé ọjọjọ́ ni ìbá sọ̀rọ̀, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n Ṣùgbọ́n ẹ̀mi kan ní ó wà nínú ènìyàn àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye Ènìyàn ńláńlá kì íṣe ọlọ́gbọ́n, Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé Ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn Kíyèsí i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín Èmi fetísí àròyé yín, nígbà tí ẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀nyín yóò sọ Àní mo fíyèsí yín tinútinú sì kíyèsí i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jóòbù ní irọ́, tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀! Kí ẹ̀yín kí ó má ṣe wí pé, àwa wá ọgbọ́n ní àwárí Ọlọ́run ni ó lè bì í ṣubú, kì í ṣe ènìyàn Bí òun kò ti sọ̀rọ̀ sí mi, bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò fi ọ̀rọ̀ yín dá a lóhùn Ẹnu sì yà wọ́n, wọn kò sì dáhùn mọ́, wọ́n síwọ́ ọ̀rọ̀ ísọ́ Mo si reti, nítorí wọn kò sì fọhún, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́ wọn kò sì dáhùn mọ́ Bẹ́ẹ̀ ni èmí ò sì dáhùn nípa ti èmí, èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn Nítorí pé èmí kún fún ọ̀rọ̀ sísọ, èmí ń rọ̀ mi ni inú mi Kíyèsí i, ìkùn mi dàbí ọtí wáìnì, tí kò ní ojú-ìhò ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-àwọ̀ tuntun Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí, èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn Lótítọ́ èmí kì yóò ṣe ojúṣàájú sí ẹnìkankan, bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán Élíhù Bá Jóòbù Sọ̀rọ̀ Njẹ́ nítorí náà, Jóòbù, èmí bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ̀ mi kí o sì fetísí ọ̀rọ̀ mi! Kíyèsí i nísinsìnyí, èmí ya ẹnu mi, ahọ́n mi sì sọ̀rọ̀ ní ẹnu mi Ọ̀rọ̀ mi yóò sì jási ìdúró ṣinṣin ọkàn mi, ètè mi yóò sì sọ ìmọ̀ mi jáde dájúdájú Ẹ̀mí Ọlọ́run Ní ó tí dá mi, Àti ìmísí Olódùmáre ni ó ti fún mi ní ìyè Bí ìwọ bá le dá mi lóhùn, tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ṣẹẹsẹ níwájú mi dìdé! Kíyèsí i, bí ìwọ ṣe jẹ́ ti Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni èmí náà láti amọ̀ wá ni a sì ti dá mi pẹ̀lú Kíyèsí i, ẹrù ń lá mi kì yóò bà ọ bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi kì yóò wúwo sí ọ lára Nítòótọ́ ìwọ sọ ní etí mi, èmí sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé, Èmí mọ́, laini ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá Àláìṣẹ̀ ní èmí bẹ́ẹ̀ àìṣéédéé kò sí ní ọwọ́ mi Kíyèsí i, Ọlọ́run ti rí àìṣedéédéé pẹ̀lú mi ó kà mí sì ọ̀tá rẹ̀ Ó kàn ẹ̀ṣẹ̀ mi sínú àbà o kíyèsi ipa ọ̀nà mi gbogbo Kíyèsí i, nínú èyí ìwọ sìnà! Èmí o dá ọ lóhùn pé, Ọlọ́run tóbi jù ènìyàn lọ! Nítorí kí ni ìwọ ṣe ń báa jà, wí pé, òun kò níi sọ ọ̀rọ̀ kan nítorí iṣẹ́ rẹ̀ Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹkan, àní lẹ́ẹkẹji, ṣùgbọn ènìyàn kò róye rẹ̀ Nínú àlá, ní ojúran òru, nígbà tó orun ìjìká bá kùn ènìyàn lọ, ní sísùn lórí ìbùṣùn, Nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn, yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí, Kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínú ètè rẹ̀ Kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn Ó sì fa ọkàn rẹ̀ pàdà kúro nínú ìsà-òkú, àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣẹ̀gbé lọ́wọ́ ìdà A sì nà á lórí ibùsùn ìrọra rẹ̀ Pẹ̀lúpẹ̀lú a fi ìjà egungun rẹ̀ ti ó dúró pẹ́ nà án Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí rẹ kọ ounjẹ, ọkàn rẹ̀ sì kọ oúnjẹ dídùn Ẹran ara rẹ̀ run, títí a kò sì fi lè ríi mọ́ egungun rẹ̀ tí a kò rí sì ta jáde Àní ọkàn rẹ̀ sì súnmọ́ ìsà òkú, ẹ̀mí rẹ̀ sìsúnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ìranṣẹ́ ikú Bí oníṣẹ́ kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ẹni tí ń ṣe alágbàwí, ọ̀kan ninú ẹgbẹ̀rún láti fi ọ̀nà pípé hàn ni, Nígbà náà ni ó ṣe oore ọ̀fẹ́ fún un ó sì wí pé, gbà á kúrò nínú ìlọ sínú ìsà òkú èmi ti ràá pàdà Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré, yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀ Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì se oju rere rẹ̀, o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀, òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé èmi ṣẹ̀, kò sì sí èyí tí o tọ́, mo sì ti yí èyí tí ó tọ́ po, a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi ó ti gba ọkàn mi kúrò nínú ìlọ sínú ihò, ẹ̀mí mi yóò sì rí ìmọ́lẹ̀! Wò ó! Nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run máa ń ṣe fún ènìyàn nígbà méjì àti nígbà mẹ́ta, Láti mú ọkàn rẹ padà kúrò nínú isà òkú, láti fi ìmọ́lẹ̀ alààyè mọ́ sí i Jóòbù, kíyèsìí gidigidi kí o sì fetí sí mi pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì máa sọ ọ́ Bí ìwọ bá sì ní ohun íwí, dá mi lóhùn máa sọ, nítorí pé èmi fẹ́ dá ọ láre Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbọ́ tèmi pa ẹnu rẹ mọ́ èmi ó sì kọ́ ọ ní ọgbọ́n Élíhù Pe Jóòbù Níjà Nígbà náà ni Élíhù dáhùn, ó sì wí pé Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí mi ẹ̀yin tí ẹ ní ìmòye Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò, bí adùn ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò Ẹ jẹ́ kí a ṣà ẹ̀tọ́ yàn fún ara wa ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrin wa Nítorí pé Jóòbù wí pé, Aláìlẹ́sẹ̀ ni èmi Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí, bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò ní àwòtán dídì ọgbẹ́ Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jóòbù, tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn Nítorí ó sá ti wí pé, Èrè kan kò sí fún ènìyàn, tí yóò fí máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetí sílẹ̀ sí mi ẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye Ódodi fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú àti fún Olódùmárè, tí yóò fí ṣe àìṣedéédéé! Nítorí pé ó ń sá fún ènìyàn fún ohun tí a bá ṣe, yóò sì mú olúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀ Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkúwà bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè kì yóò yí ìdájọ́ po Ta ni ó yàn ań lórí, tàbí ta ni ó fi gbogbo ayé lée lọ́wọ́ Bí ó bá gbé ayé rẹ̀ lé kìkì ara rẹ̀ tí ó sì gba ọkàn rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀, ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀ Ǹjẹ́ nisinsìnyí, bí ìwọ bá ní òye, gbọ́ èyí fetísí ohùn ẹnu mi Ẹni tí ó kóríra òtítọ́ ha le iṣe olórí bí Ìwọ ó hà sì dá olóótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ènìyàn búburú ní ìwọ, tàbí fún àwọn ọmọ aládé pé, ìkà ni ẹ̀yin Ańbọ̀tórí fún ẹni tí kì í ṣójúṣàájú àwọn ọmọ-aládé tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí talákà lọ Nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe Ní ìṣẹ́jú kán ni wọn ó kú, láàrin ọ̀gànjọ́ àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́, wọn a sì kọjá lọ A sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀ Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa-ọ̀nà ènìyàn, òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí ojìjì ikú, níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsí ẹnìkan, kí òun kí ó sì mú lọ sínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run Òun ó sì fọ́ àwọn alágbára túútúú láìní ìwádìí, a sì fi ẹlòmìíràn dípò wọn, nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn, ó sì yí wọn po ní òru bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di ìtẹ́rẹ́ pọ̀ Ó kọlù wọ́n nítorí ìwà búburú wọn níbi tí àwọn ẹlòmìíràn rí i, nítorí pé wọ́n padà sẹ́yìndà sí i, wọn kò sì fi yè sí ipa ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, kí wọn kí ó sì mú igbe ẹkún àwọn tálákà lọ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, òun sì gbọ́ igbe ẹkún aláìní ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi Nígbà tí ó bá pa ojú rẹ̀ mọ́, ta ni yóò lè rí i Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe é orilẹ̀ èdè tàbi sí ènìyàn kan ṣoṣo Kí àgàbàgebè kí ó má báà jọba kí wọn kí ó má di ìdẹ̀wò fún ènìyàn Nítorí pé ẹnìkan ha lè wí fún Ọlọ́run pé, èmi jẹ̀bí èmi kò sì ní ṣẹ̀ mọ́ Èyí tí èmi kò rí ìwọ fi kọ́ mi bi mo bá sì dẹ́sẹ̀ èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ Íṣe bí ti inú rẹ̀ pe òun ó san ẹ̀ṣẹ̀ padà Ǹjẹ́ òun yóò san án padà bí ìwọ bá kọ̀ ọ́ láti jẹ́wọ́ tàbí ìwọ ìbá fẹ́ kì í ṣe èmi Pẹ̀lúpẹ̀lú ohun tí ìwọ mọ̀, sọ ọ! Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fún mi, àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí í ṣe ọlọ́gbọ́n tí ó sì gbọ́ mi pé, Jóòbù ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣe aláìgbọ́n Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jóòbù wò dé òpin, nítorí ìdahùn rẹ̀ dà bí i ti ènìyàn búburú Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ó pàtẹ́wọ́ ní àárin wa, ó sì sọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ sí Ọlọ́run Olótìítọ́ Ni Ọlọ́run Elíhù sì wí pe Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé, òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóò já sí fún ọ, tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ Èmi ó dá ọ lóhùn àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ Ṣíjú wo ọ̀run kí o rí i, ki o sì bojúwo àwọ̀sánmọ̀ tí ó ga jù ọ lọ Bí ìwọ bá sẹ̀ kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí Tàbí bí àìṣedéédéé rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọ fí fún u, tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bí ìwọ òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n mú ni kígbe wọ́n kigbe nípa apá àwọn alágbára Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé, Níbo ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru Tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọn ẹranko ayé lọ, tí ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùn nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ asán bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì í rí i, ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ń bẹ níwájú rẹ, ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè Ṣùgbọ́n nísinsìnyí nítorí tí ìbínú rẹ̀ kò tí ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́, òun kò ha lè hun ímọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà búrubú bí Nítorí náà ní Jóòbù se ya ẹnu rẹ̀ lásán ó ṣọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìsí ìmọ̀ Elíhù sì tún sọ̀rọ̀ wí pé Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fi hàn ọ́ nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jínjìn wá, èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké nítòótọ́ ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀ Kíyèsí i, Ọlọ́run ni alágbára, kò sì gàn ènìyàn ó ní agbára ní ipá àti òye Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà Òun kì ímú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo, ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́ Àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n, Nígbà náà ni o ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn, wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ́lú ìgbéraga wọn Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́, ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedéédéé Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín, wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀ra, àti ọdún wọn nínú afẹ́ Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́, wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé, wọ́n á sì kú láìní òye Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní àyé kó ìbínú jọ wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá dà wọ́n Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe, ẹ̀mí wọn a sì wà nínú àwọn oníwà Sódómù Òun gba òtòsì nínú ìpọ́njú wọn, a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínu ìnira wọn Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó sì dè ọ lọ láti inú ìhágágá síbi gbòòrò, sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀ ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ a jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́ Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bàà tàn ọ́ láti jẹ́ kí títóbi èyà mú ọ sìnà Ọ̀rọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí Tàbi ipa agbára rẹ Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké àwọn orilẹ̀ èdè kúrò ní ipò wọn Máa sọra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búrubú Nítori èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ Kíyèsí i, Ọlọ́run á gbé-ni-ga nípa agbára rẹ̀ ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí òun Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un, tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga, ti ènìyàn ni yín nínú orin Olúkúlùkù a máa rí i ènìyàn a máa wòó ní òkèrè, Kíyèsí i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi ọjọ́ sílẹ̀, kí wọn kí ó kán bí òjò ní odò, tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀, tí ó sì fi ń gbìn lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ènìyàn Pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni lè imọ́ ìtànká àwọ̀sánmọ̀, tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀ Kíyèsí i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ ká ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀ Nitorí pé nípa wọn ní ń ṣe dájọ́ àwọn orílè èdè ènìyàn ó sí ń pèsè oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèje ó sì rán sí ẹni olódì Ariwo àrá rẹ̀ fi ìjì hàn ní ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú wí pé, ó súnmọ́ etílé! Ọlọ́run Kì í Pọ́n Ni Lójú Láìnídìí Ayà sì fò mi si èyí pẹ̀lú, ó sì kúro ní ìpò rẹ̀ Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀, àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo, Mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná Òun kan fọ̀ ramúramù ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá òhun kì yóò sì dá àrá dúró nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀ Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu ohùn ńláńlá ni íṣe tí àwa kò le mọ̀ Nítori tí ó wí fún Sínóó pé, Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé, àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, àti fún òjò ńlá agbára rẹ̀ Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀ ó sì tún dá olúkúlùkù ẹ̀nìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ, wọn a sì wà ni ipò wọn Láti ìhà gúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá, àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọ̀sánmọ̀ ká Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fí ìdí-omi fún ni, ibú-omi á sì sún kì Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọ̀sánmọ̀ wúwo, a sì tú àwọ̀sánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn Àwọn wọ̀nyí i káàriri nípà ìlànà rẹ̀, kí wọn kí ó lé ṣe ohunkohun tí ó pa láṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé Ó mú àwọ̀sánmọ̀ wá, ìbá ṣẹ fún ìkìlọ̀, tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn Jóòbù, dẹtí sílẹ̀ sí èyí dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run Ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run sọ wọ́n lọ́jọ̀, tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọ̀sánmọ̀ rẹ̀ dán Ìwọ mọ ti àwọ̀sánmọ̀ í fòó lọ, iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ Aṣọ rẹ̀ ti máa gbóná, nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúsù mú ayé dákẹ́ Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró sinsin, tí ó sì dàbí dígi tí ó yọ̀ dà Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un nítorí pé àwa kò le ílàdí ọ̀rọ̀ nítorí òkùnkùn wa A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀ Tàbí ẹnìkan lèwí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbémi mù Ṣibẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí oòrùn tí ń dán nínú àwọ̀sánmọ̀, ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì fẹ́ wọn mọ́ Góòlù dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rùn ńlá Nipa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀ ó ré kọjá ní ipá nínú ìdájọ́ àtí títí bi oun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́ Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀ òun kì í se ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé Ọlọ́run Pe Jóòbù Níjà Ígbà náà ní Olúwa dá Jóòbù lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìní ìgbirò ṣu ìmọ̀ ní òkùnkùn Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dámi lóhùn Níbo ni ìwọ wà nígbà ti mo fi ìpìnlẹ̀ ayé sọlẹ̀ Wí bí ìwọ bá mòye Ta ni ó fi ìwọ̀ rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ Lórí ibo ni a gbé kan ìpìnlẹ̀ rẹ̀ mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀, Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ Kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn áńgẹ́lì hó ìhó ayọ̀ Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi òkun mọ́, nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá, Nígbà tí mo fi àwọ sánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri se ọ̀já ìgbà nú rẹ̀, Nígbà tí mo ṣe òpin fún-un, tí mo sì se bèbè àti ìlẹ̀kùn, Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá, níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbà ọjọ́ rẹ̀ wá ìwọ sì mú ìlà oòrùn mọ ipò rẹ̀, Kí ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú, ki a lè gbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀ Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdì amọ̀, kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn búburú, apá gíga yóò sì ṣẹ́ Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá A ha sílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ rí bí, ìwọ sì rí ilẹ̀kùn òjìji òkú Ìwọ mòye ibú ayé bí Sọ bí ìwọ bá mọ gbogbo èyí Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé Bí ó ṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀, Tí ìwọ í fi mú un lọ síbi àlá rẹ̀, tí ìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀ Ìwọ mọ èyí, nitorí nígbà náà ni a bí ọ Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀ Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì Sínóò lọ rí bí, kìwọ sì rí ilé ìṣúrà òjò rí, Tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu, dé ọjọ́ ogun àti ìjà Ọ̀nà wo ǹi ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń ya, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé Ta ni ó la ipadò fún ẹkun omi, àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá, Láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí, ní ihà níbi tí ènìyàn kò sí Láti tẹ́ ilẹ̀ tútù, aṣálẹ̀ àti ẹgàn lọ́rùn láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde Òjò ha ní baba bí Tàbí ta ni o bí ikùn ìṣẹ ìrì Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run Omi di lile bí òkúta, ojú ibú ńlá sì dìlù pọ̀ Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Píléyádè dáradára Tàbí ìwọ le tún di Ìràwọ̀ Óríónù Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Másárótì jáde wá nígbà àkókò wọn Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Béárì pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè dé àwọ̀sánmọ̀, kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́ Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kí ó le lọ, ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ó sì wí fún wọn pé, àwa nìyí Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí ayé tàbí tí ó fi òye sínú ọkàn Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọ̀ sánmọ̀ Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde, Nígbà tí erupẹ̀ di líle, àti ògúlùtú dípò Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọ̀rọ̀ kìnnìún lọ́rùn, Nígbà tí wọ́n bá ń mọ́lẹ̀ nínú ihò tí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ Ta ni ó ń pèsè ohun jíjẹ fún ìwọ, nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń ké pe Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń fò kiri nítorí àìní ohun jíjẹ Agbára Ọlọ́run Ìwọ mọ àkókò ìgbà tíàwọn ewúrẹ́ orí àpáta ìbímọ Ìwọ sì lè kíyèsí ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pè, ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ, Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bí mọ, wọ́n sì mú ìkáànú wọn jáde Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́n dàgbà nínú ọ̀dàn wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn Ta ni ó jọ̀wọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oko lọ́wọ́ Tàbí ta ní ó tú ìdè kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́, Èyí tí mo fi ihà ṣe ilé fún, àti ilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀ Ó rẹ́rìnín sí ariwo ìlú, bẹ́ẹ̀ ni Òun kò sì gbọ́ igbe darandaran Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjókòó rẹ̀, Òun asì má a wá ewé tútù gbogbo rí Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí Tàbí, ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru Ìwọ le fi òkò tata de àgbáǹréré nínú aporo Tàbí ó jẹ́ máa fa ìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀ lée nítorí agbára rẹ̀ pọ̀ ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́ Ìwọ le gbẹ́kẹ̀ le pé, yóò mú èso oko rẹ̀ wá sílé, àti pé yóò sì kó ọ jọ sínu àká rẹ Ìyẹ́ abo ògòǹgò ń fi ayọ̀ fì Ṣùgbọ́n a kò le fi àká we ara wọn ní ìyẹ́ àti ìhùhù Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀, a sì mú wọn gbóná nínú ekuru Tí ó sì gbàgbé pé, ẹ̀sẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́, tàbí pé ẹranko ìgbẹ́ lè tẹ̀ wọ́n fọ́ Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bí ẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀ asán ni iṣẹ́ rẹ̀, láì ní ìbẹ̀rù Nítorí pé Ọlọ́run kò fún-un ní ọgbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí tàbí ṣé Ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ sí agbára rẹ̀ ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fòó bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà ṣẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹ́kẹ́pẹ́kẹ́, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbé ilẹ̀ mì, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbàá gbọ́ pé, ìró ipè ni Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà! Ó sì gbóhùn ogun lókè réré, ara àwọn balógun àti ariwo ogun wọn Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fò sókè tí ó sì mọ ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúsù Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè kí ó sì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta, lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ́ kiri, ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀, níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Élífásì Ọlọ́run Kì í Fi Ìyà Jẹ Olódodo Ígbà náà ni Élífásì, ará Témà dáhùn wí pé Bí àwa bá fi ẹnu lé e, láti bá ọ sọ̀rọ̀, ìwọ o ha banújẹ́ Ṣùgbọ́n ta ni ó lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹnu láìsọ Kíyèsí i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn, ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró, ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọ lù ọ́ ara rẹ kò lélẹ̀ Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ Èmi bẹ̀ ọ́ rántí Ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀ Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń se ìtùlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé, nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnníun àti eyín àwọn ẹ̀gbọ̀rọ̀ kìnnìún ní a ká Ógbó kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ, àwọn ẹ̀gbọrọ kìnnún sísanra ni a túká kiri Ǹjẹ́ nísinsìn yìí a fí ohun lílùmọ́ kan hàn fún mi, etí mi sì gbà díẹ̀ nínú rẹ̀ Ní ìrò ínú lojú ìrán òru, nígbà tí oorun èjìkà kùn ènìyàn Ẹ̀rù bà mí àti ìwárìrì tí ó mú gbogbo egungun mi jí pépé Nígbà náà ni iwin kan kọjá lọ ní iwájú mi, irun ara mi dìde ró ṣánṣán Ó dúró jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀, àwòrán kan hàn níwájú mi, ìdákẹ́ rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run, ènìyàn kò ha le mọ̀ ju Ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí Kíyèsí i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, nínú àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ ní ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀ Áńbọ̀ńtórí àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀, ẹni tí ìbílẹ̀ wọ́n jẹ́ sí erùpẹ̀ tí yóò di rírun kòkòrò A pa wọ́n run láti òwúrọ̀ di alẹ́, wọ́n gbé láé láìrí ẹni kà á sí A kò ha ké okùn ìye wọ̀n kúrò bí Wọ́n kú, àní láìlọ́gbọ́n Jóòbù Rẹ Ara Rẹ̀ Sílẹ̀ Olúwa dá Jóòbù lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wi pé ẹni tí ń wá ẹ̀sùn yóò bá Olódùmarè wíjọ́ bí Ẹni tí ń bá Ọlọ́run jiyàn jẹ́ kí ó dáhùn! Nígbà náà ni Jóòbù dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé, Kíyèsí i, èmi kò jámọ́ ohun kankan ohun kí ni èmi ó dà Èmi ó fi ọwọ́ le ẹnu mi Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kò rí ìdáhùn kankan lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì ní sọ ọ́ mọ́ Nígbà náà ní Olúwa sọ̀rọ̀ fún un láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé Di àmùrè gíri ní ẹgbẹ́ rẹ, èmi ó bi ọ léèrè, kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun Fi ọlá ńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́, tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bi ara ní aṣọ Mú ìrúnu ìbínú rẹ jáde kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀, kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn Sin gbogbo wọn pa pọ̀ nínú erùpẹ̀, kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú Nígbà náà ní èmi ó yàn ọ́ pé, ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là Ǹjẹ́ nísinsìnyí kíyèsí Béhámótì tí mo dá pẹ̀lú rẹ òun ha máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù Wò o nísinsìnyí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ Òun a máa jù ìru rẹ̀ bí i igi kédarì Isan itan rẹ̀ dijọ pọ̀ Egungun rẹ̀ ní ògùsọ̀ idẹ Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run ṣíbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́ Nítòótọ́ òkè ńláńlá ní imu ohun jíjẹ fún un wá, níbi tí gbogbo ẹranko ìgbẹ́ máa siré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀ Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótósì, lábẹ́ èèsún àti ẹrẹ̀ Igi lótósì síji wọn bò o igi àrọ̀rọ̀ odò yí i kákiri Kíyèsí i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jọ́rdánì ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀ Ẹnìkan ha lè ímú u ní ojú rẹ̀, tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀ Ọlọ́run Ń Tẹ̀ṣíwájú Láti Pe Jóòbù Níjà Ǹjẹ́ ìwọ lè ífi ìwọ fa Lefíátanì, ọ̀nì ńlá jáde Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀ Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní ímú, tàbí fi ìwọ̀ gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí Ìwọ ó ha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí Ìwọ hà lè ba saré bí ẹni pé ẹyẹ ni, tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀ Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí Wọn ó ha pín láàrin àwọn oníṣòwò Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin awọ rẹ̀, tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ipẹja Fi ọwọ́ rẹ lée lára, ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ̀ẹ́ mọ́ Kiyèsí àbá nípaṣẹ̀ rẹ ní asán ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi Ta ni ó ṣáájú ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san-án fún un Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara rẹ, tàbi ipá rẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́ Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì ẹ̀yìn rẹ Ta ni ó lè sí ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá Ipẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀ ó pàdé pọ̀ tímọ́tímọ́ bí àmì èdìdì Èkíní fi ara mọ́ èkejì tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárin wọn Èkíní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀ wọ́n lẹ̀ wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n Nípa sísin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ mọ́, ojú rẹ̀ a sì dàbí ìpénpéjú òwúrọ̀ Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́ iná ti jáde wá, ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde Láti imu rẹ ni èéfín ti jáde wá, bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìféfé lábẹ́ rẹ̀ Èémi rẹ̀ tinábọ ẹ̀yin, ọ̀wọ́ iná sì ti ẹnu rẹ̀ jáde Ní ọrún rẹ̀ ní agbára kù sí, àti ìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀ Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀, wọ́n múra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn nípò Àyà rẹ̀ dúró gbagigbagi bí òkúta, àní ó le bi ìyá ọlọ Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, àwọn alágbára bẹ̀rù nítorí ìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbi ọfà, ẹni tí ó sá a kò lè rán an Ó ká ìrin sí bi koríko gbígbẹ àti idẹ si bi igi híhù Ọfà kò lè mú un sá òkúta kànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àkékù koríko Ó ka ẹṣin sí bí àkékù idi koríko ó rẹ́rin-ín sí mímì ọ̀kọ̀ Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀, ó sì tẹ́ ohun mímú ṣónṣó sórí ẹrẹ̀ Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò ó sọ̀ agbami òkun dàbí kólòbó ìkunra Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀ ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀, tí a dá láìní ìbẹ̀rù Ó bojú wo ohun gíga gbogbo, ó sì nìkan já sí ọba lórí gbogbo àwọn ọmọ ìgbéraga Ìrònúpìwàdà Jóòbù Ígbà náà ní Jóòbù dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo, àti pé, kò si ìro inú tí a lè fa sẹ́yìn kurò lọ́dọ̀ rẹ Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ làíní ìmọ̀ Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyi tí èmi kò mọ̀, ohun tí ó ṣe ìyànu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye Ìwọ wí pé, gbọ́ tèmi báyìí, èmi ó sì sọ èmi ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ yóò sì dá mi lóhùn Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ojú mi ti rí ọ Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi, mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú Bẹ́ẹ̀ ó sì rí, lẹ́yìn ìgbàtí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Jóòbù, Olúwa sì wí fún Élífásì, ara Témà pé, mo bínú sí ọ, àti sí àwọn ọrẹ́ rẹ méjèèjì, nítorí pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀, níti èmi, ohun tí ó tọ́, bí Jóòbù ìránṣẹ́ mi ti sọ Nítorí náà, ẹ mú akọ ẹgbọ̀rọ̀ màlúù méje, àti àgbò méje, kí ẹ sì tọ̀ Jóòbù ìránṣẹ́ mi lọ, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sísun fún ara yín Jóòbù ìránṣẹ́ mi yóò sì gbàdúrà fún yin nítorí pé àdúrà rẹ̀ ní èmi yóò gbà kí èmi kí ó má ba ṣe si yín bí ìsìnà yín, níti pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi bi Jóòbù ìránṣẹ́ mi ti ṣe Bẹ́ẹ̀ ní Élífásì, ara Tẹ́mà, àti Bílídádì, ará Ṣúà, àti Sófárì, ará Námà lọ, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pẹ̀ṣẹ fún wọn Olúwa sì gba àdúrà Jóòbù Olúwa sì yí ìgbèkùn Jóòbù padà, nígbà tí ó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ Olúwa sì bù sí ohun gbogbo ti Jóòbù ní rí ní ìṣẹ́po méjì ohun tí ó ní tẹ́lẹ̀ rí Nigbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí wọ́n báa jẹun nínú ilé rẹ̀ Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì sìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí Olúwa ti mú bá a Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owo kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ju ìsáá jú rẹ̀ lọ ẹgbàá-méje àgùntàn, ẹgbàá-mẹ́ta ràkùnmí, àti ẹgbẹ̀rún àjàgà ọdá-màlúù, àti ẹgbẹ̀rún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ó sì ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta Ó sì sọ orúkọ àkọ̀bí ní Jẹ́mímà, àti orúkọ èkejì ni Késíà àti orúkọ ẹ̀kẹta ní Kérén-hápúkì Àti ní gbogbo ilẹ̀ náà, a kò rí obìnrin tí ó ní ẹwà bí ọmọ Jóòbù baba wọ́n sì pínlẹ̀ fún wọn ninú àwọn arákùnrin wọn Lẹ́yìn èyí Jóòbù wà ní ayé ní ogóje ọdún, ó sì rí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àní ìran mẹ́rin Bẹ́ẹ̀ ni Jóòbù kú, ó gbó, ó sì kún fún ọjọ́ púpọ̀ Ìjìyà Jẹ́ Èṣo Àìṣòdodo Ó jẹ́ pé nísinsìn yìí bí ẹnìkan bá wà tí yóò dá wa lóhùn Tàbí ta ni nínú àwọn ènìyàn mímọ́ tí ìwọ ó wò Nítorí pé ìbínú pa aláìmòye, ìrunú a sì pa òpè ènìyàn Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n lulẹ̀, ṣùgbọ́n lójú kan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu, a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè, bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa jẹ ẹran, tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀kún lọ kó, àwọn ìgárá sì gbé ohun ìní wọn mì Bí ìpọ́njú kò bá ti inú erùpẹ̀ jáde wá ni, tí ìyọnu kò ti ilẹ̀ jáde wá Ṣùgbọ́n a bí ènìyàn sínú wàhálà, gẹ́gẹ́ bí ìpẹ́pẹ́ iná ti máa ń ta sókè Sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní èmi lè máa ṣe àwárí, ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi lè máa fi ọ̀rọ̀ mi lé Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí, ohun ìyanu láìní iye Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayé tí ó sì ń rán omi sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀ Láti gbé àwọn orilẹ̀ èdè lékè kí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu Ó yí ìmọ̀ àwọn alárèékérekè po, bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdàwọ́lé wọn sẹ Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú arékerekè ara wọn, àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tari ṣubú ní ògèdèǹgbé Wọ́n sáre wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru Ṣùgbọ́n ó gba talákà là ní ọwọ́ idà, lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún talákà àìsòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́ Kíyèsíi, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí, nítorí náà, má ṣe gan ìbàwí Olódùmarè Nítorí pé òun a mú ni lára kan, a sì di ìdì ìtura, ó ṣá lọ́gbẹ́, ọwọ́ rẹ̀ á sì mú jìnnà Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà, àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ Nínu ìyànu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú àti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà A ó pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ iná ahọ́n bẹ́ẹ̀ ní ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìparun tí ó bá dé Ìrin ìparun àti ti ìyàn ni ìwọ yóò rìn bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò bẹ̀rù ẹranko ilẹ̀ ayé Nitorí pé ìwọ ó bá òkúta ìgbẹ́ múlẹ̀, àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wà ìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò sìnà Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú ọmọ rẹ ó sì pọ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko ìgbẹ́ Ìwọ yóò wọ iṣà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́, bí àpò-ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀ Kíyèsí i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí! Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ire ara rẹ ni Ìdáhùn Jóòbù Jóòbù sì dáhùn ó si wí pé Áà! à bá lè wọ̀n ìbìnújẹ́ mi nínú òṣùwọ̀n, kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òṣùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀! Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ìbá wúwo jú iyánrìn òkun lọ nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé Nítorí pé ọfà Olódùmárè wọ̀ mi nínú, oró èyí tí ọkàn mi mú ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko, tàbí ọ̀dá-màlúù a máa dún sórí ìjẹ rẹ̀ A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀, tàbi adùn ha wà nínú fúnfún eyin Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò, òun ni ó dàbí oúnjẹ mi tí kò ní adùn Áà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi Àní Ọlọ́rin ìbá jẹ́ pa mí run, tí òun ì bá jẹ́ siwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò Nígbà náà ní èmi ì bá ní ìtùnú síbẹ̀, àní èmi ì bá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù Agbára mi iṣe agbára òkúta bí, tàbí ẹran ara iṣe idẹ Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi ọgbọ́n ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá, kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódumáarè sílẹ̀ Àwọn ará mi ṣọ̀tẹ̀ bí odò sólo bí ìṣàn gúru omi odò sólo, wọ́n ṣàn kọjá lọ Tí ó dúdú nítorí omi dídì, àti níbi tí odò dídì gbé lùmọ̀ sí Nígbà kúgbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ ṣànlọ, nígbà tí òòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn Ìyà ọ̀nà wọn a sì yípadà sí apá kan, wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run Ẹgbẹ́ ogun Témà ń wòye àwọn ọwọ́ àrò Sébà ń dúró dè wọ́n Wọ́n já lulẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lée wọ́n débẹ̀, wọ́n sì dààmú Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ẹ̀yin dàbí wọn ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí Èmi ó ha wí pé, Ẹ mú ohun fún mi wá, tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín Tàbí, ẹgbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni, tàbí, ẹrà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́ kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti sìnà Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tó ṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbàwí yín já sí Ẹ̀yin ṣè bí ẹ ó bá ọ̀rọ̀ àti ohùn ẹnu tí ó takú wí tí ó dà bí afẹ́fẹ́ Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba, ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín Ẹ má wò mi! Nitorí pé ó hàn gbangba pé Ní ojú yín ni èmi kì yóò sèké Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀ àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí Àìṣedédé ha wà ní ahọ́n mi Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù Jóòbù Ha Ni Ìrètí Bí Sé ìjà kò ha si fún ènìyàn lórí ilẹ̀ Ọjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kò ha dàbí ọjọ́ alágbàṣe Bí ọmọ-ọ̀dọ̀ tí máa ń kanjú bojúwo òjíjì àti bí alágbàṣe ti í kánjú wo ọ̀nà owó iṣẹ́ rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, Èmi wí pé nígbà wo ni èmi ó dìde Tí òru yóò sì kọjá Ó sì tó fún mi láti yí síhìn-ín yí sọ́hùn-ún Títí yóò fi di ògúlùtu erùpẹ̀ ti a fi wọ̀ mí ní aṣọ, àwọ̀ mi bù, ó sì di sísun ni Kòkòrò àti ògúlùtu erúpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ, awọ ara mi bù, o sì di sísun Ọjọ́ mi yára jù ọkọ̀ ìhunṣọ lọ, o sì di lílò ní àìní ìrètí Áà! Ránti pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi ojú mi kì yóò padà rí rere mọ́ Ojú ẹni tí ó rí mi, kì yóò rí mi mọ́ ojú rẹ̀ tẹ̀ mọ́ra mi, èmi kò sí mọ́ Bí ìkùùku tí i túká, tí í sì fò lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sí ipò òkú tí kì yóò padà wa mọ́ Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ní ipò rẹ̀ kì yóò mọ̀ ọn mọ́ Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́, èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi, èmí yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi Èmi a máa ṣe ejò òkun tàbí erinmi, tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára, ìtẹ́ mi yóò gbé ẹrù ìráhùn mi pẹ̀lú Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da ẹ̀gbọ̀n bò mi, ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rù bà mí Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti so àti ikú ju kí ń wà láàyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ O ṣú mi, èmi kò le wà títí jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀ Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọ̀kàn rẹ lé e Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀, ti ìwọ o sì máa dán anwò nígbàkúgbà! Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ, tí ìwọ o fi jọ títí èmi o fi lè dá itọ́ mi mì Èmi ti ṣẹ̀, ki ní èmi ó se sí ọ Ìwọ Olùtọ́jú ènìyàn Èéṣe tí ìwọ fi mí ṣe àmì ìtasi niwájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi si di erù-wúwo sì ara rẹ̀ Èéṣe tí ìwọ kò sì dárí ìrékọjá mi jìn, kí ìwọ kí ó sì mú aìṣédéédéé mi kúrò Ǹjẹ́ nísinsìn yìí ni èmi ìbá sùn nínú erùpẹ̀, ìwọ ìbá sì wá mi kiri ní owúrọ̀, èmi kì bá tí sí Bílídádì pé Jóòbù láti ronúpìwàdà Ígbà náà ni Bílídádì, ará Ṣúà, sì dáhùn wí pé Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkán wọ̀nyí pẹ́ tó Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfú ńlá Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí, tàbí Olódùmárè a máa fi òtítọ́ sẹ̀ bí Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ sẹ̀ sí i, ó sì gbá wọn kúrò nítorí àṣẹ wọn Bí ìwọ bá sì képe Ọlọ́run ní ìgbà àkókò, tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmáarè Ìwọ ìbá mọ́, kí ó sì dúró sinṣsin ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsìn yìí òun yóò tají fún ọ, òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀ Ìpilẹsẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í, bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yin rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì kí o sì kíyèsí ìwádìí àwọn baba wọn Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan, nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá Koríko odò ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀ tàbí èèsú ha lè dàgbà láìlómi Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò kee lulẹ̀, ó rọ dànù, ewéko mìíràn gbogbo hù dípò rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run, àbá àwọn àgàbàgebè yóò di òfo Àbá ẹni tí a ó ké kúrò, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dà bí ilé aláǹtakùn Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró, yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́ Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú òòrùn, ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀ Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká, ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀, nígbà náà ni ipò náà sẹ́ ẹ pé, Èmi kò ri ọ rí! Kíyèsí i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù àti lati inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmìíràn yóò hù jáde wá Kíyèsí i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà-búburú lọ́wọ́ títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu, àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀ ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó koríra rẹ̀, àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́ Jóòbù Fún Bílídádì Lésì Nípa Ẹ̀kọ́ Àti Ẹ̀rí Ìdajọ́ Ọlọ́run Jóòbù sì dáhùn ó sì wí pé Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́! Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run Bí ó bá ṣe pé yóò bá jà, òun kì yóò lè dálóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rùn-ún ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òún ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́ tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀ Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀ sì mì tìtì Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́ Òun nìkanṣoṣo ni ó na ojú ọ̀run lọ, ti ó sì ń rìn lórí ìgbì òkun Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Béárì, Óríónì àti Píléíádè àti yàrá púpọ̀ ti gúsù Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwàrí lọ, àní ohun ìyanu láìní iye Kíyèsí i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, èmi kò sì rí i, ó sì kọjá síwáju, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀ Kiyèsí i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn, àwọn oní rànlọ́wọ́ ti Ráhábù a sì tẹriba lábẹ́ rẹ̀ Kí ní ṣe tí èmi ò fi dá a lóhùn Tí èmi kò fi máa fi ọ̀rọ̀ àwàwí mi ṣe àwsíyé fún-un Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn, ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn, èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi Nítorí pé òun yóò lọ̀ mi lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá ó sọ ọgbẹ́ mi di pupọ̀ láìnídìí Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi, ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó! Alágbára ni, tàbí ńi ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi óò dá mi lẹ́bi bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi Olóòótọ́ ni mo ṣe, síbẹ̀ èmi kò kíyèsí ara mi, ayé mi ní èmi ìbá máa gàn Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi se sọ Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú Bí ìjàǹbá bá pani lójijì, yóò rẹ́rín-ín ìdàwọ́ aláìṣẹ̀ Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni Ǹjẹ́ nísinsìn yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ, wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀ Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eésú tí ń ṣúré lọ bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ Bí èmi bá wí pé, Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi, èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí, èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀ Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi, ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ ojú dídì wẹ ara mi, tí mo fi omi àrò wẹ ọwọ́ mi mọ́, ṣíbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihò ọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi, tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́ Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì wa tí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára Kí ẹnìkan ṣá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi, kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì se dáyà fò mí Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó tí dáré-ti mi, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi Ìsígun Eṣú Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jóẹ́lì ọmọ Pétúélì wá Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbààgbà ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín, tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín, ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn, ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kù ní ọ̀wọ́ eṣú jẹ Èyí tí ọ̀wọ́ eṣú jẹ kù ní eṣú tata jẹ Èyí tí eṣú tata jẹ kù ni eṣú apanirun mìíràn jẹ Ẹ jí gbogbo ẹ̀yín ọ̀mùtí kí ẹ sì ṣunkún ẹ pohùnréré ẹkún gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì ẹ pohùnréré ẹkún nítorí wáìnì tuntun nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín Nítorí orílẹ̀ èdè kan ti sígun sí ilẹ̀ mìíràn ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà ó ní eyín kìnnìún ó sì ní èrìgì abo kìnnìún Ó ti pa àjàrà mi run, ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò, ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di fun-fun Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúndíá tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmúre, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀ A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímú kúrò ní ilé Olúwa àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀, àwọn ìrànṣẹ́ Olúwa , Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń sọ̀fọ̀ nítorí, a fi ọkà ṣòfò ọtí wáìnì tuntún gbé, òróró ń bùṣe Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀ ẹ pohùn réré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà, nítorí àlìkámà àti nítorí ọkà báálì nítorí ìkórè oko ṣègbé Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù igi pómégánátì, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú, àti igi ápíílì, gbogbo igi igbó ni o rọ Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùn réré ẹkún ẹyín àlùfáà ẹ pohùn réré ẹkún, ẹyín ìránṣẹ́ pẹpẹ ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìrànsẹ́ Ọlọ́run mi nítorí tí a dá ọrẹ jíjẹ àti ọrẹ mímú dúró ní ilé Ọlọ́run un yín Ẹ yà ààwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú, ẹ pe àwọn àgbà, àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà jọ sí ilé Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sí képe Olúwa A! Fún ọjọ́ náà, nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, yóò de bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmare A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájú ojú wá yìí, ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú ilé Ọlọ́run wá Irúgbìn bàjẹ́ nínú ebè wọn, a sọ àká di ahoro, a wó àká palẹ̀ nítorí tí a mú ọkà rọ Àwọn ẹranko tí ń kerora tó! Àwọn agbo ẹran dààmú, nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà Olúwa , sí ọ ni èmi o ké pè, nítorí iná tí run pápa oko tútú ihà, ọwọ́ iná sí ti jó gbogbo igi igbó Àwọn ẹranko igbó gbé ojú sókè sí ọ pẹ̀lú nítorí tí àwọn iṣàn omi gbẹ, iná sí ti jó àwọn pápá oko ihà run Àwọn Jagunjagun Eṣú Ẹ fun ìpè ní Ṣíónì, ẹ sì fún ìpè ìdágàrì ní òkè mímọ́ mi Jẹ́ kí àwọn ará ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí tí ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá, nítorí ó kù sí dẹ̀dẹ̀ Ọjọ́ òkùnkùn àti òkùdù, ọjọ́ ìkùùkù àti òkùnkùn biribiri, bí ọyẹ́ òwúrọ̀ ti í la bo orí àwọn òkè ńlá àwọn ènìyàn ńlá àti alágbára ya dé, ti kó ti ì sí irú rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kì yóò sí mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, títí dé ọdún ìran dé ìran Iná ń jó níwájú wọ́n ọwọ́ iná sì ń jó lẹ́yìn wọn ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Édẹ́nì níwájú wọn, àti lẹ́yìn wọn bí ahoro ijù nítòótọ́, kò sì sí ohun tí yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin wọ́n ń ṣe láńkú láńkú lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni wọn ń fo ní orí òkè bí ariwo ọ̀wọ́ iná tí ń jó koríko gbígbẹ, bí akọni ènìyàn tí a kó jọ fún ogun Ní ojú wọn, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora púpọ̀ gbogbo ojú ní yóò ṣú dudu Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun olúkúlúkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀, wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò to ẹnìkejì rẹ̀ olúkúlukù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀ nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù ìdà wọn kì yóò gbọgbẹ́ Wọn yóò sáré síwá ṣẹ́yìn ní ìlú wọn yóò súré lórí odi, wọn yóò gùn orí ilé wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè Ayé yóò mì níwájú wọn àwọn ọ̀run yóò wárìrì òòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn ṣẹ́yìn Olúwa yóò sì bú rámu ramù jáde níwájú ogun rẹ̀ nítorí ibùdó rẹ̀ tóbi gidigidi nítorí alágbára ní òun, tí n mú ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ nítorí ọjọ́ Olúwa tóbi ó sì ní ẹ̀rù gidigidi ara ta ni ó lè gbà á Njẹ́ nítorí náà nísínsin yìí, ni Olúwa wí, Ẹ fi gbogbo ọkàn yín yípadà sí mi, àti pẹ̀lú ààwẹ̀, àti pẹ̀lú ẹkún, àti pẹ̀lú ọ̀fọ̀ Ẹ sì fa ọkàn yín ya, kì í sì í ṣe aṣọ yín, ẹ sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí tí o pọ̀ ní oore ọ̀fẹ́, ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà, kí ó sì fí ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ àní ọrẹ jíjẹ àti ọrẹ mímu fún Olúwa Ọlọ́run yín Ẹ fún ìpè ní Ṣíónì, ẹ ya ààwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ, ẹ ya ìjọ sí mímọ́ ẹ pe àwọn àgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọdé jọ, àti àwọn tí mú ọmú jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú iyẹ̀wù rẹ̀ Kí ìyàwó sì kúrò nínù ìyàrá rẹ̀ Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa , sọkún láàrin ìlorò àti pẹpẹ, sí jẹ́ kí wọn wí pé, Dá àwọn ènìyàn rẹ sí Olúwa , má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn, ti àwọn aláìkọlà yóò fi má jọba lórí wọn èéṣe tí wọn yóò fi wí láàárin àwọn ènìyàn pé, Ọlọ́run wọn há da   Nígbà náà ní Olúwa yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀, yóò sì káànú fún ènìyàn rẹ̀ Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn Yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé, Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun, àti òróró síi yín, a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn èmi kì yóò si fí yín ṣe ẹ̀gan mọ́ láàrin àwọn aláìkọlà Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín, èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro, pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí òkun ìlà oòrùn, àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀ oòrùn òkun Oòrùn rẹ̀ yóò sì gòkè, òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀ jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀, nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá, Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó, nítorí pápá-oko ihà ń rú, nítorí igi ń so èso rẹ̀, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà ń so èso ipá wọn Ǹjẹ́ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Ṣíónì, ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́, Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín, àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní Àwọn ilẹ̀ ìpàkà yóò kún fún ọkà àti ọpọ́n wọn nì yóò ṣàn jáde pẹ̀lú ọti wáìnì tuntun àti òróró Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòro ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ àwọn ogun ńlá mí tí mo rán sí àárin yín Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, titi ẹyin yóò fi yó ẹ ó sì yín orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrin Ísírẹ́lì, àti pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ati pé kò sí ẹlòmíràn ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mí láéláé Yóò sì ṣe, èmi yóò tú ẹ̀mi mí sí ara ènìyàn gbogbo àti àwọn ọmọ yín ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa ṣọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọ́kunrìn yín yóò máa ríran Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin, àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin, ní èmi yóò tú ẹ̀mi mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun àti ní àyé, ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín A á sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀ru Olúwa tó dé Yóò sí ṣe ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè orúkọ Olúwa ní a ó gbàlà nítorí ní òkè Ṣíónì àti ní Jérúsálẹ́mù ní ìgbàlà yóò gbé wà, bí Olúwa ti wí, àti nínú àwọn ìyókù tí Olúwa yóò pè A Dá Orilẹ Èdè Lẹ́jọ́ Ní ọjọ́ wọ̀n ọn nì, àti ní àkókò náà, nígbà tí èmi tún mú ìgbékùn Júdà àti Jérúsálẹ́mù padà bọ̀ Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀ èdè jọ pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí àfonífojì Jéhóṣáfátì Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi, àti nítorí Ísírẹ́lì ìní mi, tí wọ́n fọ́nká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, wọ́n sì pín ilẹ̀ mi Wọ́n si ti di ibò fún àwọn ènìyàn mi wọ́n sì ti fi ọmọdé-kùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan, wọ́n sì ta ọmọdé bìnrin kan fún ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tirè àti Ṣídónì, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Fílístínì Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹyín ṣe padà sórí ara yín Nítorí tí ẹ̀yín tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere daradara mi lọ sínú tẹ́ḿpìlì yín Àti àwọn ọmọ Júdà, àti àwọn ọmọ Jérúsálẹ́mù ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ara Gíríkì, kí ẹ̀yin báà le sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìnì wọn Kíyèsì í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Júdà, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Ṣábíà, fún orílẹ̀ èdè kan tí ó jìnnà réré Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ Ẹ kéde èyí ní àárin àwọn aláìkọlà Ẹ dira ogun, ẹ jí àwọn alágbára, Jẹ kí awọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun, Ẹ fi irin itulẹ yín rọ idà, àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀ Jẹ́ kí aláìlera wí pé, Ara mi le koko Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin aláìkọlà láti gbogbo àyíká, kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ ṣọkalẹ̀, Olúwa Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojì Jéhóṣáfátì ẹ̀yin aláìkọlà nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jòkòó láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìkọlà yí kákìri Ẹ tẹ̀ dòjé bọ̀ ọ́, nítorí ìkórè pọ́n ẹ wá, ẹ ṣọ̀kalẹ̀ nítorí ìfúntí kún, nítorí àwọn ọpọ́n kún-à-kún-wọ́sílẹ̀ nítorí ìwà búburú wọn pọ̀! Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àfonífojì ìdájọ́, nítorí ọjọ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀ ní àfonífojì ìdájọ́ Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn, àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́ Olúwa yóò sí ké ramúramú láti Ṣíónì wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jérúsálẹ́mù wá àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀, àti agbára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń gbé Ṣíónì òkè mímọ́ mi Ìgbà náà ni Jérúsálẹ́mù yóò jẹ́ mímọ́ àwọn àlejò kì yóò sì kó o mọ́ Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè-ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀, àwọn òkè kéékèèkéé yóò máa ṣàn fún wàrà gbogbo odò Júdà tí ó gbẹ́ yóò máa ṣàn fún omi Oríṣun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ile Olúwa wá, yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣítímù Ṣùgbọ́n Éjíbítì yóò di ahoro, Édómù yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro, nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Júdà, ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ Ṣùgbọ́n Júdà yóò jẹ́ ibùgbé títí láé, àti Jérúsálẹ́mù láti ìran dé ìran Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tíì wẹ̀nù Nítorí Olúwa ń gbé Síónì Jónà Sá Ní Iwájú Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jónà ọmọ Ámítaì wá, wí pé Dìde lọ sí ìlú ńlá Nínéfè kí o sì wàásù sí i, nítorí ìwà búburú rẹ̀ gòkè wá iwájú mi Ṣùgbọ́n Jónà dìde kúrò láti sá lọ sí Tásísì kúrò níwájú Olúwa , ó sì ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí Jópà, ìbí ti ó tí rí ọkọ̀ kan tí ń lọ sí Tásísì lẹ́yìn ti ó sanwó ọkọ̀, ó wọlé sínú rẹ̀, láti bá wọn lọ sí Tásísì kúrò níwájú Olúwa Nígbà náà ni Olúwa rán ìjì ńlá jáde sí ojú òkun, ìjì líle sì wà nínú òkun tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ náà dàbí ẹni pé yóò fọ́ Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ bẹ̀rù, olúkúlùkù sì ń kígbe sí ọlọ́run rẹ̀, wọ́n kó ẹrù tí ó wà nínú ọkọ̀ dà sínú òkun, kí ó bá à lè fúyẹ́ Ṣùgbọ́n Jónà sọ̀kalẹ̀ lọ sí ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ ó sì dùbúlẹ̀, ó sùn wọra Bẹ́ẹ̀ ni olórí ọkọ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, Èéṣe tí ìwọ fi sùn, ìwọ olóorun Dìde kí o ké pe Ọlọ́run rẹ! Bóyá yóò ro tiwa, kí àwa má ba à ṣègbé Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ sọ fún ara wọn pé, Wá, ẹ jẹ́ kí a sẹ́ kèké, kí àwa kí o le mọ̀ nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa Wọ́n ṣẹ́ kèké, kèké sì mú Jónà Nígbà náà ni wọn wí fún un pé, Sọ fún wa, àwa bẹ̀ ọ́, nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa Kí ni iṣẹ́ rẹ Níbo ni ìwọ ti wá Kí ni orúkọ ìlú rẹ Ẹ̀yà orílẹ̀-èdè wo sì ni ìwọ sì í ṣe Òun sì dá wọn lóhùn pé, Hébérù ni èmi, mo sì bẹ̀rù Olúwa , Ọlọ́run ọ̀run ẹni tí ó dá òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù gidigidi, wọn sì wí fún un pé, Èéṣe tí ìwọ fi ṣe èyí Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, Kí ni kí àwa ó se sí ọ kí òkun lè dákẹ́ fún wa Nítorí òkun ru, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle Òun sì wí fún wọn pé, Ẹ gbé mi, kí ẹ sì sọ mi sínú òkun, bẹ́ẹ̀ ni okun yóò sì dákẹ́ fún un yin Nítorí èmi mọ̀ pé, nítorí mi ni ẹ̀fúùfù líle yìí ṣe dé bá a yín Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà wà á kíkan láti mú ọkọ̀ wà sí ilẹ̀ ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é nítorí tí òkun túbọ̀ ru síi, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle sí wọn Nítorí náà wọ́n kígbe sí Olúwa , wọ́n sì wí pé, Olúwa àwa bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí àwa ṣègbé nítorí ẹ̀mí ọkùnrin yìí Má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa ní ọrùn, nítorí ìwọ, Olúwa , ti ṣe bí ó ti wù ọ́ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Jónà, tí wọ́n sì sọ ọ́ sínú òkun, òkun sì dẹ́kun ríru rẹ̀ Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù Olúwa gidigidi, wọn si rúbọ sí Olúwa , wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ Ṣùgbọ́n Olúwa ti pèṣè ẹja ńlá kan láti gbé Jónà mì Jónà sì wà nínú ẹja náà ni ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta Àdúrà Jónà Ngbà náà ni Jónà gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja náà wá, Ó sì wí pé Nínú ìpọ́njú mi ni mo kígbe sí Olúwa , òun sì gbọ́ ohùn mi Mo kígbe láti inú ipò òkú, mo pè fún iraǹwọ́, ìwọ sì gbọ́ ohùn mi Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú, ní àárin òkun, ìṣàn omi sì yí mi káàkiri gbogbo bíbì omi àti rírú omi ré kọjá lórí mi Nígbà náà ni mo wí pé, a ta mí nù kúrò níwájú rẹ ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ èmi yóò tún máa wo ìhà tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn ibú yí mi káàkiri, a fi koríko odò wé mi lórí Èmi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ìṣàlẹ̀ àwọn òkè ńlá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá, Olúwa Ọlọ́run mi Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi, èmi rántí rẹ, Olúwa , àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, nínú tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èké kọ àánú ara wọn sílẹ̀ Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rúbọ sí ọ Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́ Igbàlà wá láti ọdọ Olúwa Olúwa sì pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ Jónà sí orí ilẹ̀ gbígbẹ Jónà Lọ Nínéfè Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jónà wá nigbà kejì wí pé Dìde lọ sí Nínéfè, ìlú ńlá a nì, kí o sì kéde sí i, ìkéde tí mo sọ fún ọ Jónà sì dìde ó lọ sí Nínéfè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa Nínéfè jẹ́ ìlú títóbi gidigidi, ó tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta Jónà sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìlú náà lọ ní ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde, ó sì wí pé, Níwọ̀n ogójì ọjọ́ sí i, a ó bi Nínéfè wó Àwọn ènìyàn Nínéfè sì gba Ọlọ́run gbọ́ Wọ́n sì kéde ààwẹ̀, gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, bẹ̀rẹ̀ lati orí ọmọdé títí dé orí àgbà wọn Ọ̀rọ̀ náà sì dé ọ̀dọ̀ ọba Nínéfè, ó sì dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ ìgúnwà rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì jókòó nínú eérú Nígbà náà ní ó kéde rẹ̀ ni Nínéfè pé Kí a la Nínéfè já nípa àṣẹ ọba, àti àwọn àgbààgbà rẹ̀ pé Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn, tàbí ẹranko, ọ̀wọ́-ẹran tàbí agbo-ẹran, tọ́ ohunkóhun wò má jẹ́ kí wọn jẹ tàbí mu omi Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn àti ẹranko da aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, kí wọn sì kígbe kíkan sí Ọlọ́run, sì jẹ́ kí wọn yípadà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀ àti kúrò ní ìwà ìpa tí ó wà lọ́wọ́ wọn Ta ni ó lè mọ̀ bí Ọlọ́run yóò yípadà kí ó sì ronúpìwàdà, kí ó sì yípadà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwa má ṣègbé Ọlọ́run sì rí ìṣe wọn pé wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀nà ibi wọn Ọlọ́run sì ronúpìwàdà ibi tí òun ti wí pé òun yóò ṣe sí wọn, òun kò sì ṣe e mọ́ Jónà Bínú Sí Àánú Tí Ṣùgbọ́n ó ba Jónà nínú jẹ́ gidigidi, ó sì bínú púpọ̀ Ó sì gbàdúrà sí Olúwa , ó sì wí pé, Èmí bẹ̀ ọ́, Olúwa , ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ti mo sọ kọ́ ni èyi nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi Nítórí èyí ni mo ṣé sá lọ sí Tásísí ní ìṣáájú nitori èmi mọ̀ pé, Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ ní ìwọ, àti aláàánú, O lọ́ra láti bínú, O sì ṣeun púpọ̀, O sì ronúpìwàdà ibi náà Ǹjẹ́ báyìí, Olúwa , èmi bẹ̀ ọ, gba ẹ̀mí mi kúrò lọ́wọ́ mi nítorí ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láàyè lọ Nígbà náà ni Olúwa wí pé, Ìwọ́ ha ni ẹ̀tọ́ láti bínú bí Jónà sì jáde kúrò ní ìlú náà, ó sì jókòó níhà ìlà-oòrùn ìlú náà Ó sì pa àgọ́ kan níbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó ni ibòòji ní abẹ́ rẹ̀ títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà Olúwa Ọlọ́run sì pesè ìtàkùn kan, ó ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jónà kí ó lè ṣe ìji bò ó lórí láti gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀ Jónà sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ Ó sì ṣe, nígbà tí òòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn oòrùn sì pa Jónà lórí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́ Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láàyè lọ Ọlọ́run sì wí fún Jónà pé, O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà Òun sì wí pé, Mo ni ẹ̀tọ́, Ó tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú Nígbà náà ni Olúwa wí pé, Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́, tí ìwọ kò mu dàgbà tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan Ṣùgbọ́n Nínéfè ní jù ọ̀kẹ́-mẹ́fà ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun-ọ̀sìn pẹ̀lú Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ilú ńlá náà Lẹ́yìn ikú u Móṣè ìránṣẹ́ Olúwa , Olúwa sọ fún Jóṣúà ọmọ Núnì, olùrànlọ́wọ́ ọ Móṣè Mósè ìránṣẹ́ ẹ̀ mi ti kú Nísinsìn yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí ẹ múra láti kọjá odò Jọ́dánì lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Ísírẹ́lì Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹṣẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Móṣè Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti ihà u Lẹ́bánónì, àti láti odò ńlá, ti Éfúrétì—gbogbo orílẹ̀ èdè Hítì títí ó fi dé Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú ù rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mósè, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú ù rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́ Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi Kí o sì sọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Móṣè ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, Má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ Má ṣe jẹ́ kí Ìwé Ofin yìí kúrò ní ẹnu ù rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀ṣán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀ Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le Má ṣe bẹ̀rù, má sì se rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú ù rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ Báyìí ni Jóṣúà pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, Ẹ pèṣè oúnjẹ yín sílẹ̀ Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jọ́dánì yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní Ṣùgbọ́n Jóṣúà sọ fún àwọn ará a Rúbẹ́nì, àwọn ará Gádì àti fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè pé, Rántí àṣẹ tí Móṣè ìránṣẹ́ Olúwa pa fún yín Olúwa Ọlọ́run yín á fún yin ní ìsinmi, òun yóò sì fún un yín ní ilẹ̀ yìí Àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ẹran ọ̀sìin yín lè dúró ní ilẹ̀ tí Móṣè fún un yin ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì ṣùgbọ́n gbogbo àwọn jagunjagun un yín, pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun gbọdọ̀ kọjá ṣíwájú àwọn arákùnrin yín Ẹ̀yin yóò sì rán àwọn arákùnrin yín lọ́wọ́ títí Olúwa yóò fi fún wọn ní ìsinmi, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún un yín, àti títí tí àwọn pẹ̀lú yóò fi gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún wọn Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin lè padà sí ilẹ̀ ìní in yín, tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa fi fún un yin, ní agbégbé ìlà-óòrùn ti Jọ́dánì Nígbà náà ni wọ́n dá Jósúà lóhùn pé, Ohunkóhun tí ìwọ pa láṣẹ fún wa ni àwa yóò ṣe ibikíbi tí ìwọ bá rán wa ni àwa yóò lọ Gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́ran sí Móṣè nínú ohun gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò máa gbọ́ tìrẹ Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lúù rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà pẹ̀lú u Móṣè Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí ọ̀rọ̀ rẹ, tí kò sì ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ, nínú ohun gbogbo tí ìwọ yóò paláṣẹ fún wọn, pípa ni a ó pa á Kí ìwọ ṣáà ṣe gírí, kí ó sì mú àyà le! Òòrùn Dúró Jẹ́ Ní báyìí tí Adoni-Sédékì ọba Jérúsálẹ́mù gbọ́ pé Jóṣúà ti gba Áì, tí ó sì ti pa wọ́n pátapáta tí ó sì ṣe sí Áì àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jẹ́ríkò àti ọba rẹ̀, àti bí àwọn ènìyàn Gíbíónì ti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Ísírẹ́lì, tí wọ́n sì ń gbé nítòsí wọn Ìbẹ̀rù sì mú òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ torí pé Gíbíónì jẹ́ ìlú tí ó ṣe pàtàkì, bí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ọba ó tóbi ju Áì lọ, gbogbo ọkùnrin rẹ̀ ní ó jẹ́ jagunjagun Nítorí náà Adoni-Sédékì ọba Jérúsálẹ́mù bẹ Hóámù ọba Hébúrónì, Pírámù ọba Jámútù, Jáfíà ọba Lákíṣì àti Débírìe ọba Égílónì Wí pe, Ẹ gòkè wá, kí ẹ sì ràn mi lọ́wọ́ láti kọlu Gíbíónì, nítorí tí ó ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ́lú Jóṣúà ti àwọn ará Ísírẹ́lì Àwọn ọba Ámórì máràrùn, ọba Jérúsálẹ́mù, Hébúrónì, Jámútù, Lákíṣì àti Égílónì-kó ara wọn jọ, wọ́n sì gòkè, àwọn àti gbogbo ogun wọn, wọ́n sì dojú kọ Gíbíónì, wọ́n sì kọ lù ú Àwọn ará Gíbíónì sì ránṣẹ́ sí Jóṣúà ní ibùdó ní Gílígálì pé Ẹ má ṣe fi ìránṣẹ́ yín silẹ̀ Ẹ gòkè tọ̀ wà wá ní kánkán kí ẹ sì gbà wá là Ẹ ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Ámórì tí ń gbé ní orílẹ̀ èdè òkè dojú ìjà kọ wá Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà gòkè lọ láti Gílígálì, pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, àti akọni nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé, Má ṣe bẹ̀rù wọn Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojú kọ ọ́ Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wọ́de ogun ní gbogbo òru náà láti Gílígálì, Jóṣúà sì yọ sí wọn lójijì Olúwa mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Ísírẹ́lì, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gíbíónì Ísírẹ́lì sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Bẹti-Hórónì, ó sì pa wọ́n dé Ásékà, àti Mákédà Bí wọ́n sì tí ń sá ní iwájú Ísírẹ́lì ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ní ọ̀nà láti Bẹti-Hórónì títí dé Ásékà, Olúwa rọ yìnyín ńlá sí wọn láti ọ̀run wá, àwọn tí ó ti ipa yìnyín kú sì pọju àwọn tí àwọn ará Ísírẹ́lì fi idà pa lọ Ní ọjọ̀ tí Olúwa fi àwọn ọmọ Ámórì lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, Jóṣúà sọ fún Olúwa níwájú àwọn ará Ísírẹ́lì Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gíbíónì, Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí àfonífojì Áíjálónì Bẹ́ẹ̀ ni òòrùn náà sì dúró jẹ́, òṣùpá náà sì dúró, títí tí ìlú náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀ta rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú ìwé Jáṣárì Oòrùn sì dúró ní agbede-méjì ọ̀run, kò sì wọ̀ ní ìwọ̀n odindi ọjọ́ kan Kò sí ọjọ́ tí o dàbí rẹ̀ ṣaájú tàbí ní ẹ̀yìn rẹ̀, ọjọ́ tí Olúwa gbọ́ ohùn ènìyàn Dájúdájú Olúwa jà fún Ísírẹ́lì! Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì padà sí ibùdó ní Gílígálì Ní báyìí àwọn ọba Ámórì márùn-ún ti sá lọ, wọ́n sì fara pamọ́ nínú ihò àpáta kan ní Mákédà, Nígbà tí wọ́n sọ fún Jósúà pé, a ti rí àwọn ọba máràrùn, ti ó fara pamọ́ nínú ihò àpáta ní Mákédà, ó sì wí pé, Ẹ yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò àpáta náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin sí ibẹ̀ láti ṣọ́ ọ Ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe dúró! Ẹ lépa àwọn ọ̀ta yín, ẹ kọlù wọ́n làti ẹyìn, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó dé ìlú wọn, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín tí fi wọ́n lé yín lọ́wọ́ Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà àti àwọn ọmọ ogun pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ ogun àwọn ọba máràrùn run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Jóṣúà ní ibùdó ogun ní Mákédà ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Ísírẹ́lì Jósúà sì wí pe, Ẹ ṣi ẹnu ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba máràrùn jáde wá fún mi Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúró nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jérúsálẹ́mù, Hẹ́búrónì, Jámútù, Lákíṣì àti Égílónì Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọba náà tọ Jóṣúà wá, ó pe gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, ó sì sọ fún àwọn olórí ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, Ẹ sún mọ́ bí, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín lé ọrùn àwọn ọba wọ̀nyí Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wá sí iwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ lé ọrùn wọn Jóṣúà sì sọ fún wọn pé, Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le Báyìí ni Olúwa yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀ta yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà Nígbà náà ni Jóṣúà kọlù wọ́n, ó sì pa àwọn ọba máràrùn náà, ó sì so wọ́n rọ̀ ní orí igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí orí igi títí di ìrọ̀lẹ́ Nígbà tí oòrun wọ̀, Jóṣúà pàṣẹ, wọ́n sì ṣọ̀ wọ́n kalẹ̀ kúró ní orí igi, wọ́n sì gbé wọn jù sí inú ihò àpáta ní ibi tí wọ́n sápamọ̀ sí Wọ́n sì fi òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà, tí ó sì wà níbẹ̀ di òní yìí Ní ọjọ́ náà Jóṣúà gba Mákédà Ó sì fi ojú idà kọlu ìlú náà àti ọba rẹ̀, ó sì run gbogbo wọn pátapáta, kò fi ẹnìkan sílẹ̀ Ó sì ṣe sí ọba Mákédà gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí ọba Jẹ́ríkò Nígbà náà ní Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Mákédà lọ sí Líbínà wọ́n sì kọlù ú Olúwa sì fi ìlú náà àti ọba rẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ Ìlú náà àti gbogbo àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni Jóṣúà fi idà pa Kò fi ẹnìkan sílẹ̀ ní ibẹ̀ Ó sì ṣe sí ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí ọba Jẹ́ríkò Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo ará Ísírẹ́lì, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Líbínà lọ sí Lákíṣì ó sì dótì í, ó sì kọlù ú Olúwa sì fi Lákísì lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, Jóṣúà sì gbà á ní ọjọ́ kéjì Ìlú náà àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀ ní ó fi idà pá gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Líbínà Ní àkókò yìí, Hórámì ọba Gésérì gòkè láti ran Lákíṣì lọ́wọ́, ṣùgbọ́n Jóṣúà ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ títí ti kò fi ku ẹnìkan sílẹ̀ Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Lákíṣì lọ sí Égílónì wọ́n sì dótì í, wọ́n sì kọ lù ú Wọ́n gbà á ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì run gbogbo ènìyàn ibẹ̀ pátapáta, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Lákísì Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì sí láti Égílónì, lọ sí Hébúrónì, wọ́n sì kọlù ú Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n sìti idà bọ̀ ọ́, pẹ̀lú ọba rẹ̀, gbogbo ìletò wọn àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀ Wọn kò dá ẹnìkan sí Gẹ́gẹ́ bí ti Égílónì, wọ́n run un pátapáta àti gbogbo ènìyàn inú rẹ̀ Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ yí padà, wọ́n sì kọlu Débírì Wọ́n gba ìlú náà, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú wọn, wọ́n sì fi idà pa wọ́n Gbogbo ènìyàn inú rẹ̀ ni wọ́n parun pátapáta Wọn kò sì dá ẹnìkankan sí Wọ́n ṣe sí Débírì àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ti ṣe sí Líbínà àti ọba rẹ̀ àti sí Hébúrónì Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà ṣẹ́gun gbogbo agbégbé náà, ìlú òkè, Négéfi, ìlú ẹsẹ̀ òkè ti ìhà ìwọ̀-óòrùn àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè pẹ̀lú gbogbo ọba, wọn kò dá ẹnìkankan sí Ó pa gbogbo ohun alààyè run pátapáta, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti pàṣẹ Jóṣúà sì ṣẹ́gun wọn láti Kadeṣi Báníyà sí Gásà àti láti gbogbo agbègbè Góṣénì lọ sí Gíbíónì Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí àti ilẹ̀ wọn ní Jósúà sẹ́gun ní ìwọ́de ogun ẹ́ẹ̀kan, nítorí tí Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jà fún Ísírẹ́lì Nígbà náà ni Jóṣúà padà sí ibùdó ní Gílígálì pẹ̀lú gbogbo Ísírẹ́lì A Sẹ́gun Àwọn Ọba Ìhà Àríwá Nígbà tí Jábínì ọba Hásórù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó ránṣẹ́ sí Jóbábù ọba Madónì, sí ọba Ṣímírónì àti Ákíṣáfù, àti sí àwọn ọba ìhà àríwá tí wọ́n wà ní orí òkè ní aginjù, gúsù ti Kínérótù, ní ẹsẹ̀ òkè ìwọ̀-oòrùn àti ní Nafotu Dórì ní ìwọ̀-oòrùn sí àwọn ará Kénánì ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn sí àwọn Ámórì, Hítì, Pérísì àti Jébúsì ní orí òkè àti sí àwọn Hífì ní ìsàlẹ̀ Hámónì ní agbégbé Mísípà Wọ́n sì jáde pẹ̀lú gbogbo ogun wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun ńlá, wọ́n sì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun Gbogbo àwọn ọba yìí pa ọmọ ogun wọn pọ̀, wọ́n sì pa ibùdó sí ibi omi Mérómù láti bá Ísírẹ́lì jà Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé, Má ṣe bẹ̀rù wọn nítorí ní àkókò yìí ní ọ̀la, gbogbo wọn ni èmi yóò fi lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ní pípa Ìwọ yóò já iṣan ẹ̀yìn ẹṣin wọn, ìwọ yóò sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yọ sí wọn ní òjijì ní ibi omi Meromù, wọ́n sì kọlù wọ́n, Olúwa sì fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ Wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì lépa wọn ní gbogbo ọ̀nà títí dé Sídónì ńlá, sí Mísíréfótì-Máímù, àti sí Àfonífojì Mísípà ní ìlà-óòrùn, títí tí kò fi ku ẹnìkankan sílẹ̀ Jóṣúà sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ Ó sì já iṣan ẹ̀yìn ẹsẹ̀ ẹṣin wọn ó sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn Ní àkókò náà Jóṣúà sì padà sẹ́yìn, ó sì ṣẹ́gun Hásórù, ó sì fi idà pa ọba rẹ̀ Wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ Wọ́n sì pa wọ́n run pátapáta, wọn kò sì fi ohun alàyè kan sílẹ̀ ó sì fi iná sun Hásóri fúnrarẹ̀ Jóṣúà sì kó gbogbo àwọn ìlú ọba àti ọba wọn, ó sì fi idà pa wọ́n Ó sì run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ Sí bẹ̀ Ísírẹ́lì kò sùn ọ̀kankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkè kékèké, àyàfi Hásórì nìkan tí Jóṣúà sun Àwọn ará Ísírẹ́lì sì kó gbogbo ìkógún àti ohun ọ̀sìn ti ìlú náà fún ara wọn Wọ́n sì fi idà pa gbogbo ènìyàn títí wọ́n fi run wọ́n pátapáta, kò sí ẹni tí ó wà láàyè Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní Mósè pàṣẹ fún Jóṣúà, Jóṣúà sì ṣe bẹ́ẹ̀ Kò fi ọ̀kankan sílẹ̀ láìṣe nínú gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mósè Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà gba gbogbo ilẹ̀ náà ilẹ̀ òkè, gbogbo Nẹ́gébù, gbogbo agbégbé Gósénì, ẹsẹ̀ òkè ti ìwọ̀-oòrùn, aginjù àti àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ísírẹ́lì, láti òkè Hálakì títí dé òkè Séírì, sí Báálì-Gádì ní Àfonífojì Lẹ́bánónì ní ìsàlẹ̀ òkè Hámónì Ó sì mú gbogbo ọba wọn, ó sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n Jóṣúà sì mú gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí jagun ní ọjọ́ pípẹ́ Kò sí ìlú kan tí ó bá àwọn ará Ísírẹ́lì ṣe àdéhùn àlàáfíà, àyàfi àwọn ará Hífì tí wọ́n ń gbé ní Gíbíónì, gbogbo wọn ló bá a jagun Nítorí Olúwa fúnrà rẹ̀ ní ó sé ọkàn wọn le, kí wọn kí ó lè bá Ísírẹ́lì jagun, kí òun lè pa wọ́n run pátapáta, kí wọn má sì ṣe rí ojúrere, ṣùgbọ́n kí ó lè pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Ní àkókò náà ni Jóṣúà lọ tí ó sì run àwọn ará Ánákì kúrò ní ilẹ̀ òkè, láti Hébúrónì, Débírì, àti ní Ánábù, àti gbogbo ilẹ̀ Júdà, àti kúrò ní gbogbo ilẹ̀ òkè Ísírẹ́lì Jóṣúà sì run gbogbo wọn pátapáta àti ìlú wọn Kò sí ará Ánákì kankan tí ó sẹ́kù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì bí kò ṣe ní Gásà, Gátì àti Ásídódù Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà sì gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè, ó sì fi fún Ísírẹ́lì ní ilẹ̀-ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nípa ẹ̀yà wọn Ilẹ̀ náà sì sinmi ogun Orúkọ Àwọn Ọba Tí A Ṣẹ́gun Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì, láti Ánónì-Gọ́gi dé Okè Hámónì, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù Síhónì ọba àwọn Ámorì, tí ó jọba ní Hésíbónì Ó ṣe àkóso láti Ároérì tí ń bẹ ní etí Anoni-Gọ́gì, láti àárin Jọ́ọ́jì dé Odò Jábókì, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ámónì Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gílíádì Ó sì se àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kínẹ́rétì sí ìhà Òkun ti aginjù , sí Bẹti-Jésímótù, àti láti gúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Písígà Àti agbégbé Ógù ọba Básánì, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Ráfíátì, ẹni tí ó jọba ní Ásítarótù àti Édírì Ó se àkóso ní orí Okè Hámónì, Sálékà, Básánì títí dé ààlà àwọn ènìyàn Gésúrì àti Máákà, àti ìdajì Gílíádì dé ààlà Síhónì ọba Hésíbónì Mósè ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì borí wọn Mósè ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, àwọn ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè kí ó jẹ́ ohun ìní wọn Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì, láti Báálì Gádì ní Àfonífojì Lẹ́bánónì sí Okè Hálákì, èyí tí O lọ sí ọ̀nà Sérì ọba Jẹ́ríkò ọ̀kan ọba Áì ọ̀kan ọba Jérúsálẹ́mù ọ̀kan ọba Hébúrónì ọ̀kan ọba Jámútù ọ̀kan ọba Lákíṣì ọ̀kan ọba Égílónì ọ̀kan ọba Gésérì ọ̀kan ọba Débírì ọ̀kan ọba Gédérì ọ̀kan ọba Hómà ọ̀kan ọba Árádì ọ̀kan ọba Líbínà ọ̀kan ọba Ádúlámù ọ̀kan ọba Mákedà ọ̀kan ọba Bétélì ọ̀kan ọba Tápuà ọ̀kan ọba Héférì ọ̀kan ọba Áfẹ́kì ọ̀kan ọba Lásárónì ọ̀kan ọba Mádónì ọ̀kan ọba Hásórù ọ̀kan ọba Símírónì-Mérónì ọ̀kan ọba Ákísáfù ọ̀kan ọba Tánáákì ọ̀kan ọba Mégídò ọ̀kan ọba Kádésì ọ̀kan ọba Jókínámù ni Kamẹli ọ̀kan ọba Dórì ọ̀kan ọba Góyímì ní Gílígálì ọ̀kan ọba Tásà ọ̀kan gbogbo àwọn ọba náà jẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n Ilẹ̀ Tí Ó Kù Láti Gbà Nígbà tí Jóṣúà sì darúgbó tí ọjọ́ orí rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ, Olúwa sọ fún un pé, Ìwọ ti darúgbó púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ sì kù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún yín láti gbà Èyí ni ilẹ̀ tí ó kù gbogbo àwọn agbègbè àwọn Fílístínì, àti ti ara Gésúrì láti odò Ṣíhónì ní ìlà oòrùn Éjíbítì sí agbégbé Ékírónì ìhà àríwá, gbogbo rẹ̀ ni a kà kún Kénánì láti gúsù, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kénánì, láti Árà ti àwọn ará Sídónì títí ó fi dé Áfékì, agbègbè àwọn ará Ámórì, Àti ilẹ̀ àwọn ara Gíbálì, àti gbogbo àwọn Lẹ́bánónì dé ìlà-oòrùn, láti Baalì-Gádì ní ìṣàlẹ̀ Okè Hámónì dé Lebo-Hámátì Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbégbé òkè, láti Lẹ́bánónì sí Mísiréífótì-Máímù, àní, gbogbo àwọn ará Sídónì, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Ísírẹ́lì Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ, pín ilẹ̀ yìí ní ilẹ̀-ìní fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn án àti ìdajì ẹ̀yà Mànásè Àwọn ìdajì ẹ̀yà Mánásè tí ó kù, àti àwọn Rúbẹ́nì àti àwọn Gádì ti gba ilẹ̀ ìní, tí Mósè ti fún wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jọ́dánì bí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn Ó sì lọ títí láti Áreórì tí ń bẹ létí Ánónì-Gógì, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárin Gógì, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Médébà títí dé Díbónì Gbogbo ìlú Síhónì ọba àwọn Ámórì, tí ó ṣe àkóso ní Hésíbónì, títí dé ààlà àwọn ará Ámónì Àti Gílíádì, ní agbégbé àwọn ènìyàn Gésúrì àti Máákà, gbogbo Okè Hámónì àti gbogbo Básánì títí dé Sálẹ́kà, Ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ógù ní Básánì, tí ó jọba ní Áṣítarótù àti Édérì, ẹni tí ó kù nínú àwọn Réfáítì ìyókù Mósè ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì kò lé àwọn ará Géṣúrì àti Máákà jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárin àwọn ará Ísírẹ́lì títí di òní yìí Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Léfì ni kò fi ogún kankan fún, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé ọrẹ àfinásun sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún tiwọn, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún wọn Èyí ni Mósè fi fún ẹ̀yà Rúbẹ́nì ni agbo ilé sí agbo ilé Láti agbégbé Áréórì ní etí Ánónì Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrin Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Médébà sí Héṣibónì àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Débónì, Bámótì, Báálì, Bẹti-Báálì Míónì, Jáhásì, Kédẹ́mótì, Méfáátì, Kíríátaímù, Síbímà, Sẹrétì Sháárì lórí òkè ní àfonífojì Bẹti-Péórì, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà, àti Bẹti-Jésímátì gbogbo ìlú tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀e àti gbogbo agbégbé Síhónì ọba Ámórì, tí ó ṣe àkóso Héṣíbónì Mósè sì ti sẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ìjòyè Mídíánì, Éfì, Rékémì, Súrì, Húrì àti Rébà, àwọn ọmọ ọba pàmọ̀pọ̀ pẹ̀lú Síhónì tí ó gbé ilẹ̀ náà Ní àfikún àwọn tí a pa ní ogun, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa Bálámù ọmọ Béórì alásọtẹ́lẹ̀ Ààlà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni etí odò Jọ́dánì Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ ni ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní agbo ilé ní agbo ilé Èyí ni ohun tí Mósè ti fi fún ẹ̀yà Gádì, ní agbo ilé ní agbo ilé Agbègbè ìlú Jásérì, gbogbo ìlú Gílíádì àti ìdajì orílẹ̀ èdè àwọn ọmọ ará Ámónì títí dé Áróérì ní ẹ̀bá Rábà àti láti Hésíbónì lọ sí Ramati-Mísífà àti Bétónímù, àti láti Móhánáimù sí agbégbé ìlú Débírì, àti ní àfonífojì Bẹti-Hárámù, Bẹti-Nímírà, Súkótìọ àti Sáfónì pẹ̀lú ìyókù agbégbé ilẹ̀ Síhónì ọba Héṣíbónì Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ jẹ́ ogún àwọn ọmọ Gádì, ní agbo ilé ní agbo ilé Èyí ni ohun tí Mósè ti fi fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè, èyí ni pé, fún ìdajì ìdílé irú ọmọ Mánásè, ní agbo ilé ní agbo ilé Ilẹ̀ náà fẹ̀ dé Máháníámù àti gbogbo Básánì, gbogbo agbégbé ilẹ̀ Ógù ọba Básánì, èyí tí í se ibùgbé Jáírì ní Básánì, ọgọ́ta ìlú, ìdajì Gílíádì, àti Ásítarótù àti Édírérì Èyí ni fún irú àwọn ọmọ Mákírì ọmọ Mánásè fún ààbọ̀ àwọn ọmọ Mákírì, ní agbo ilé ní agbo ilé Èyí ni ogún tí Mósè fi fún wọn nígbà tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù ní ìhà kéjì Jọ́dánì ní ìlà-oòrùn Jẹ́ríkò Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yà Léfì, Mósè kò fi ogún fún un Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní ogún wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn Pínpín Ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn Jọ́dánì Ìwọ̀nyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà gẹ́gẹ́ bí ogún ní ilẹ̀ Kénánì, tí Élíásérì àlùfáà, Jósúà ọmọ Núnì àti olórí ẹ̀yà àwọn agbo ilé Ísírẹ́lì pín fún wọn Ìbò ni a fi pín ìní wọn fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn án ààbọ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ọwọ́ Mósè Mósè ti fún àwọn ẹ̀yà méjì àti ààbọ̀ ní ogún wọn ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Léfì ni kò fi ìní fún ní àárin àwọn tí ó kù Àwọn ọmọ Jósẹ́fù sì di ẹ̀yà méjì, Mánásè àti Éfíráimù Àwọn ọmọ Léfì kò gba ìpín ní ilẹ̀ náà bí kò ṣe àwọn ìlú tí wọn yóò máa gbé, pẹ̀lú pápá oko tútù fún ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran wọn Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Ísírẹ́lì pín ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Àwọn ọkùnrin Júdà wá sí ọ̀dọ̀ Jósúà ní Gílígálì Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnè ti Kénísì wí fún un pé, Ìwọ rántí ohun tí Olúwa sọ fún Mósè ènìyàn Ọlọ́run ní Kadesi-Báníyà nípa ìwọ àti èmi Mo jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa rán mi láti Kádesi-Báníyà lọ rin ilẹ̀ náà wò Mo sì mú ìròyìn wá fún un gẹ́gẹ́ bí o ti dá mi lójú, ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin mi tí wọ́n bá mi lọ mú àyà àwọn ènìyàn já Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi fi gbogbo ọkàn tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run mi Ní ọjọ́ náà, Mósè búra fún mi pé, Ilẹ̀ tí ẹsẹ̀ rẹ ti rìn ni yóò jẹ́ ìní rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ láéláé, nítorí pé ìwọ fi tọkàntọkàn wà Pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run mi Bí Olúwa ti ṣe ìlérí, o ti mú mi wà láàyè fún ọdún márùn-úndínláàádọ́ta láti ìgbà tí ó ti sọ fún Mósè Nígbà tí Ísírẹ́lì ń rìn kiri nínú aṣálẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà sì nìyí lónìí, ọmọ ọgọ́rin ọdún ó lé márùn-ún Síbẹ̀ èmi ní agbára lónìí, bí ìgbà tí Mósè rán mi jáde Èmi sì ní agbára láti jáde fún ogun nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí mo ti wà ní ígbà náà Nísinsìnyí fi ìlú orí òkè fún mi èyí tí Olúwa ṣe ìlérí fún mi ní ọjọ́ náà Ìwọ gbọ́ ní ìgbà náà pé àwọn ọmọ Ánákì ti wà ní ibẹ̀, àti àwọn ìlú wọn tóbi, pé ó sì se olódi, ṣùgbọ́n bí Olúwa ba fẹ́, èmi yóò lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua súre fun Kélẹ́bù ọmọ Jéfún ó si fun un ní Hébúrónì ni ilẹ̀ ìni Bẹ́ẹ̀ ni Hébúrónì jẹ́ ti Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ará Kánísì láti ìgbà náà, nítorí tí ó tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì tọkàntọkàn Nígbà náà ni ilẹ̀ náà sinmi ogun Ìpín Fún Ẹ̀yà Júdà Ìpín fún ẹ̀yà Júdà, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbégbé Édómù, títí dé ihà Síní ní òpin ìhà gúsù Ààlà wọn ní ìhà gúsù bẹ̀rẹ̀ láti etí òpin ìhà gúsù Òkun Iyọ̀, Ó sì lọ sí gúsù Sikopioni Pasi lọ títi dé Sínì àti sí iwájú ìhà gúsù Kadesi Báníyà Nígbà náà ó sì tún kọjá Hésórónì lọ sí Ádárì, ó sì tún yípo yíká lọ sí Kákà Ó tún kọjá lọ sí Ásímónì, ó sì papọ̀ mọ́ Wádì ti Éjíbítì, ó parí sí òkun Èyí ni ààlà wọn ní ìhà gúsù Ààlà wọn ní ìhà ìlà-oòrùn ní Òkun Iyọ̀ títí dé ẹnu Jọ́dánì Ààlà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etí òkun ní ẹnu Jọ́dánì, ààlà náà sì tún dé Bẹti-Hógílà, ó sì lọ sí ìhà àríwá Bẹti-Árábà Ààlà náà sì tún dé ibi Òkúta Bóhánì ti ọmọ Rúbẹ́nì Ààlà náà gòkè lọ títí dé Débírì láti Àfonífojì Ákórì, ó sì yípadà sí àríwá Gílígálì, èyí tí ó dojú kọ iwájú Ádúmímù gúsù ti Gọ́ọ́jì Ó sì tẹ̀síwájù sí apá omi Ẹbi Ṣéméṣì, ó sì jáde sí Ẹni Rógélì Ààlà náà sì tún gòkè lọ sí Àfonífojì Bẹni Hínómù ní ìhà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gúsù ti Jébúsì Ó sì gòkè lọ sí orí òkè tí ó wà lórí Àfonífojì Hínómù ní òpín àríwá àfonífojì Réfáímù Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Néfítóà, ó sì jáde sí ìlú Okè Éífírónì, ó sì lọ sí apá ìṣàlẹ̀ Báálà, Ààlà tí ó yípo láti Báálà lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí okè Séírì, ó sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Jéárímù , ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Bẹti-Sẹ́mẹ́sì, ó sì kọja lọ sí Tímínà Ààlà náà sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Ékírónì, ó sì yípadà lọ sí Síkerónì, ó sì yípadà lọ sí Okè Báálà, ó sì dé Jábínẹ́ẹ́lì, ààlà náà sì parí sí òkun Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbégbé Òkun ńlá Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Júdà ní agbo ilé wọn Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Jóṣúà, ó fi ìpín fún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè, ipin ní Júdà-Kiriati Áríbà, tí í ṣe Hébúrónì Kélẹ́bù sì lé àwọn ọmọ Ánákì mẹ́ta jáde láti Hébúrónì-Ṣéṣáyì, Áhímónì, àti Tálímáì-ìran Ánákì Ó sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Débírì Kélẹ́bù sì wí pé, Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Ákísà fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati Séférì, tí ó sì gbà á ní ìgbeyàwó Ótíniẹ́lì ọmọ Kénásì, arákùnrin Kélẹ́bù, sì gbà á, báyìí ni Kélẹ́bù sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Ákísà fún un ní ìyàwó Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Ákísà lọ sí ọ̀dọ̀ Ótíniẹ̀lì, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀ Nígbà nàà ni Ákísà sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kélẹ́bù sì béèrè pé, Kí ni kí èmi ṣe fún ọ Ó sì dáhùn pé, Ṣe ojúrere àtàtà fún mi Níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní ilẹ̀ ní Negefi fun mi ní ìsun omi pẹ̀lú Báyìí ni Kélẹ́bù fún un ní ìsun omi ti òkè àti ti ìṣàlẹ̀ Èyí ni ilẹ̀ ini ẹ̀yà àwọn ọmọ Júdà gẹ́gẹ́ bi ìdílé wọn Ìlú ìpẹ̀kun gúsù ti ẹ̀yà Júdà ní Négéfi ní ààlà Édómù niwọ̀nyí Kabísélì, Édérì, Jágúrì, Kínà, Dímónà, Ádádà, Kédéṣì, Hásórì, Ítina, Sífì, Télémù, Bíálótì, Hasori-Hádátà, Kerioti-Hésírónì , Ámámù, Sẹ́mà, Móládà, Hasa-Gádà, Hésímónì, Bẹti-Pélétì, Hasari-Ṣúálì, Bíáṣébà, Bísíótíyà, Báálà, Hímù, Ésémù, Elitóládì, a Késílì, Hórímà, Síkílágì, Mádímánà, Sánsánà, Lébáótì, Sílímù, Háínì àti Rímónì, àpapọ̀ ìlú mọ́kàndín ní ọgbọ̀n àti àwọn ìlétò wọn Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹsẹ̀ òkè Ésítaólì, Sórà, Áṣínà, Sánóà, Eni-Gánímù, Tápúà, Énámù, Jámútì, Ádúlámù, Sókò, Ásekà, Ṣááráímù, Ádítaímù àti Gédérà , ìlú mẹ́rìnlá àti àwọn ìletò wọn Sénánì, Hádáṣà, Mígídánì-Gádì, Díléánì, Mísípà, Jókítẹ́lì, Lákísì, Bósíkátì, Égílónì, Kábónì, Lámásì, Kítílísì, Gédérótì, Bẹti-Dágónì, Náámà àti Mákédà, ìlú mẹ́rìndín ní ogún àti ìletò wọn Líbínà, Étíérì, Áṣánì, Hífítà, Ásínà, Nésíbù, Kéílà, Ákísíbì àti Máréṣà, ìlú mẹ́sàn àti àwọn ìletò wọn Ékírónì, pẹ̀lú ibùgbé àti àwọn ìletò rẹ̀ tó yí i ká, ìwọ̀-oòrùn Ékírónì, gbogbo èyí tí ń bẹ nítòòsí Áṣídódù, pẹ̀lú àwọn ìletò wọn, Áṣídódù, agbégbé ìlú rẹ̀ àti ìletò àti Gásà, ìlú rẹ̀ àti ìletò, títí ó fi dé Wádì ti Éjíbítì àti agbégbé òkun ńlá Ní ilẹ̀ òkè náà Ṣámírì, Játírì, Sókò, Dánà, Kíríátì-Sánà , Ánábù, Ésítémò, Ánímù, Gósénì, Hólónì àti Gílónì, ìlú mọ́kànlá àti ìletò wọn Árabù, Dúmà, ṣ Éṣánì, Jánímù, Bẹti-Tápúà, Áfékà, Húmútà, Kíríátì Áríbà àti Síori ìlú mẹ́sàn án àti àwọn ìletò rẹ̀ Máónì, Kámẹ́lì, Sífì, Jútà, Jésérẹ́lì, Jókídíámù, Sánóà, Káínì, Gíbíátì àti Tímà ìlú mẹ́wàá àti àwọn ìletò wọn Hálíúlì, Bẹti-Súrì, Gédórì, Máárátì, Bẹti-Ánótì àti Élítékónì ìlú mẹ́fà àti àwọn ìletò wọn Kiriati Báálì àti Rábà ìlú méjì àti ìletò wọn Ní asálẹ̀ Bẹti-Árábà, Mídínì, Sékákà, Níbíṣánì, Ìlú Iyọ̀ àti Ẹni-Gẹ́dì, ìlú mẹ́fà àti ìletò wọn Júdà kò lè lé àwọn ọmọ Jébúsì jáde, tí wọ́n ń gbé ní Jérúsálẹ́mù Àwọn ará Jébúsì sì ń gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn Júdà títí dí òní Ìpín Fún Ẹ̀yà Éfúráímù Àti Mànásè Ìpín ti Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò, ó sì la aṣálẹ̀ kọjá láti ibẹ̀ sí ọ̀nà ihà sí òkè ìlú Bẹ́tẹ́lì Ó sì tẹ̀ṣíwájú láti Bẹ́tẹ́lì kọjá lọ sí agbègbè àwọn ará Áríkì ní Atárótù, Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn agbègbè àwọn ará Jéfílétì, títí dé ilẹ̀ ìṣàlẹ̀ Bẹti Hórónì, àní dé Gésérì, ó sì parí sí etí òkun Báyìí ni Mànásè àti Éfúráímù, àwọn ọmọ Jósẹ́fù gba ilẹ̀ ìní wọn Èyí ni ilẹ̀ Éfúráímù, ní agbo ilé agbo ilé Ààlà ìní wọn lọ láti Atarotu-Ádárì ní ìlà oòrùn lọ sí Okè Bẹti-Hórónì Ó sì lọ títí dé òkun Láti Míkímétatì ní ìhà àríwá, ó sì yí lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Taanati-Sílò, ó sì kọjá ní ẹ̀bá rẹ̀ lọ sí Jánóà ní ìlà-oòrùn Láti Jánóà ó yípo lọ sí gúsù sí Átarótì àti Náárà, ó sì dé Jẹ́ríkò, ó sì pin sí odò Jọ́dánì Láti Tápúà ààlà náà sì lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, ní Kana-Ráfínì, ó sì parí ní òkun Èyí ni ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Éfúráímù, ní agbo ilé agbo ilé Ó tún mú àwọn ìlú àti ìletò wọn tí ó yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Éfúráímù tí ó wà ní àárin ìní àwọn ọmọ Mánásè Wọn kò lé àwọn ara Kénánì tí ń gbé ni Gésérì kúrò, titi di oni yìí ni àwọn ara Kébáni ń gbé láàárin àwọn ènìyàn Éfúráímù, Ṣùgbọ́n wọ́n mú wọ́n sìn Èyí ní ìpín ẹ̀yà Mànásè tí í ṣe àkọ́bí Jósẹ́fù, fún Mákírì, àkọ́bí Mánásè Mákírì sì ni babańlá àwọn ọmọ Gílíádì, tí ó ti gba Gílíádì àti Básánì nítorí pé àwọn ọmọ Mákírì jẹ́ jagunjagun ńlá Nítorí náà ìpín yìí wà fún ìyókù àwọn ènìyàn Mánásè ní agbo ilé Ábíésérì, Hélékì, Ásíríélì, Sékémù, Héférì àti Ṣémídà Ìwọ̀nyí ní àwọn ọmọ ọkùnrin Mánásè ọmọ Jósẹ́fù ní agbo ilé wọn Nísinsìn yìí Sẹloféádì ọmọ Héférì, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírì, ọmọ Mánásè, kò ní ọmọkùnrin, bí kò se àwọn ọmọbìnrin, tí orúkọ wọn jẹ́ Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tásà Wọ́n sì lọ bá Élíásárì àlùfáà, Jóṣúà ọmọ Núnì, àti àwọn olórí wí pé, Olúwa pàṣẹ fún Mósè láti fún wa ní ìní ní àárin àwọn arákùnrin wa Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà fún wọn ní ìní pẹ̀lú àwọn arákùnrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa Ìpín ilẹ̀ Mànásè sì jẹ́ ìsọ̀rí mẹ́wàá ní ẹ̀bá Gílíádì àti Básánì ìlà oòrùn Jọ́dánì, Nítorí tí àwọn ọmọbìnrin ẹ̀yà Mànásè gba ìní ní àárin àwọn ọmọkùnrin Ilẹ̀ Gílíádì sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ọmọ Mánásè Agbégbé Mánásè sì fẹ̀ láti Áṣírìu títí dé Míkímẹ́tatì ní ìlà oòrùn Sékémù Ààlà rẹ̀ sì lọ sí ìhà gúsù títí tó fi dé ibi tí àwọn ènìyàn ń gbé ní Tápúà, Ààlà náà sì tún tẹ̀ṣíwájú lọ sí gúsù dé Kana-Ráfínì Àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti Éfúráímù wà ní àárin àwọn ìlú Mánásè, ṣùgbọ́n ààlà Mánásè ni ìhà àríwá Ráfínì, ó sì pin sí òkun Ìhà gúsù ilẹ̀ náà jẹ́ ti Éfúráímù, ṣùgbọ́n ìhà àríwá jẹ́ ti Mánásè Ilẹ̀ Mánásè dé òkun, Ásérì sì jẹ́ ààlà rẹ̀ ní àríwá, nígbà Ísákárì jẹ́ ààlà ti ìlà-oòrùn Ní àárin Ísákárì àti Ásérì, Mánásè tún ni Bẹti-Ṣánì, Íbílémù àti àwọn ènìyàn Dórì, Énídórì, Táánákì àti Mégídò pẹ̀lú àwọn abúlé tí ó yí wọn ká Ṣíbẹ̀, àwọn ọmọ Mánásè kò lè gba àwọn ìlú wọ̀nyí, nítorí àwọn ará Kénánì ti pinnu láti gbé ní ilẹ̀ náà Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Ísírẹ́lì di alágbára, wọ́n mú àwọn ọmọ Kénánì sìn, ṣùgbọ́n wọn kò lé wọn jáde pátapáta Àwọn ẹ̀yà Jósẹ́fù méjèèje sì sọ fún Jóṣúà pé, Kí ló dé ìwọ fi fún wa ní ìpín ilẹ̀ kan àti ìdá kan ní ìní Nítorí àwa jẹ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí Olúwa ti bùkún lọ́pọ̀lọpọ̀ Jóṣúà dá wọn lóhùn pé, Bí ẹ bá pọ̀ bẹ́ẹ̀, tí òkè ìlú Éfúráímù bá kéré fún yin, ẹ gòkè lọ sí igbó kí ẹ sì sán ilẹ̀ òkè fún ara yín ní ibẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Pérísì àti ará Réfì Àwọn ènìyàn Jósẹ́fù dáhùn, Òkè kò tó fún wa, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ará Kénánì tí ó gbé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ ní Bẹti-Ṣánì àti àwọn ìletò àti àwọn tí ń gbé ní àfonífojì Jésírẹ́ẹ́lì ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin Ṣùgbọ́n Jóṣúà sọ fún àwọn ilé Jósẹ́fù fún Éfúráímù àti Mánásè pé, Lóòtọ́ ni ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ẹ sì jẹ́ alágbára Ẹ̀yin kí yóò sì ní ìpín kan ṣoṣo Ṣùgbọ́n ilẹ̀ orí òkè igbo jẹ́ tiyín pẹ̀lú Ẹ ṣán ilẹ̀ náà, òpin rẹ̀ yóò jẹ́ tiyín pátapáta Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kénánì ní kẹ̀kẹ́ ogun irin, tí ó sì jẹ́ pé wọ́n ní agbára, ṣíbẹ̀ ẹ lè lé wọn jáde Pínpín Ilẹ̀ Tí Ó Kù Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì péjọ ní Ṣílò, wọ́n si kó Àgọ́ Ìpàdé ní ibẹ̀ Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn, ṣùgbọ́n ó ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kò tí ì gba ogún ìní wọn Báyìí ni Jóṣúà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe dúró pẹ́ tó, kí ẹ tó gba ilẹ̀ ìní tí Olúwa , Ọlọ́run àwọn baba yín ti fi fún yín Ẹ yan àwọn ọkùnrin mẹ́ta nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan Èmi yóò rán wọn jáde láti lọ bojúwo ilẹ̀ náà káàkiri, wọn yóò sì ṣe àpèjúwe rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìní ẹni kọ̀ọ̀kan Nígbà náà ni wọn yóò padà tọ̀ mí wá Ẹ̀yin yóò sì pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje kí Júdà dúró sí ilẹ̀ rẹ̀ ni ìhà gúsù àti ilé Jósẹ́fù ní ilẹ̀ rẹ̀ ní ìhà àríwá Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá kọ àpèjúwe ọ̀nà méjèèje ilẹ̀ náà, ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi ní ibí, èmi ó sì ṣẹ́ gègé fún yín ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Léfì kò ní ìpín ní àárin yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà Olúwa ni ìní wọ́n Gádì, Rúbẹ́nì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jọ́dánì Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn Bí àwọn ọkùnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn láti fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà, Jóṣúà pàṣẹ fún wọn pé, Ẹ lọ kí ẹ sì fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà kákiri, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀ Lẹ́yìn náà kí ẹ padà tọ̀ mí wá, èmi yóò sì fún yin ní ibí ní Sílòi ní iwájú Olúwa Báyìí ni àwọn ọkùnrin náà lọ, wọ́n sì la ilẹ̀ náà já Wọ́n sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sí orí ìwé kíká ní ìlú, ní ọ̀nà méje, wọ́n sì padà tọ Jóṣúà lọ ní ibùdó ní Ṣílò Jóṣúà sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Sílò ní iwájú Olúwa , Jóṣúà sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀ Ìbò náà sì wá sórí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, ní agbo ilé, agbo ilé Ilẹ̀ ìpín wọn sì wà láàárin ti ẹ̀yà Júdà àti Jósẹ́fù Ní ìhà àríwá ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ ní Jọ́dánì, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jẹ́ríkò ní ìhà àríwá, ó sì forílé ìwọ̀-oòrùn sí ìlú òkè, jáde sí asálẹ̀ Bẹti-Áfẹ́nì Láti ibẹ̀ ààlà náà tún kọjá lọ sí ìhà gúsù ní ọ̀nà Lúsì, ó sìdé Afaroti-Ádárì, ní orí òkè tí ó wà ní gúsù Bẹti-Hórónì Láti òkè tí ó kọjú sí Bẹti-Hórónì ní gúsù ààlà náà yà sí gúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí Kiriati-Báálì , ìlú àwọn ènìyàn Júdà Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn Ìhà gúsù bẹ̀rẹ̀ ní ìpẹ̀kun Kiriati-Jéárímù ní ìwọ̀-oòrùn, ààlà náà wà ní ibi ìsun omi Nẹ́fítóà Ààlà náà lọ sí ìṣàlẹ̀ ẹṣẹ̀ òkè tí ó kọjú sí Àfonífojì Bẹni-Hínómù, àríwá Àfonífojì Réfáímù O sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Àfonífojì Hínómù sí apá gúsù gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ìlú Jébúsì, ó sì lọ bẹ́ẹ̀ títí dé Ẹbi Rósẹ́lì Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni Ṣẹ́mẹ́sì, ó tẹ̀ṣíwájú dé Gélíótì tí ó kọjú sí òkè Pasi Ádúmímù, ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Okúta Bóhánì ọmọ Rúbẹ́nì Ó tẹ̀ṣíwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Bẹti-Árábà, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Bẹti-Hógíládì, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò Jọ́dánì ní gúsù Èyí ni ààlà ti gúsù Odò Jọ́dánì sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó ṣàmì sí ìní àwọn ìdílé Bẹ́ńjámínì ní gbogbo àwọn àyíká wọn Ẹyà Bẹ́ńjámínì ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí Jẹ́ríkò, Bẹti-Hógílà, Emeki-Késísì, Bẹti-Árábà, Sẹ́máráímù, Bẹ́tẹ́lì, Áfímù, Párà, Ófírà Kẹ́fárì, Ámónì, Ófínì àti Gébà, àwọn ìlú méjìlá àti ìletò wọn Gíbíónì, Rámà, Béérótì, Mísípà, Kéfírà, Mósà, Rẹ́kẹ́mù, Írípẹ́ẹ́lì, Tárálà, Sélà, Háléfì, ìlú Jébúsì , Gíbíà àti Kíríátì, àwọn ìlú mẹ́rìnlá àti ìletò wọn Èyí ni ìní Bẹ́ńjámínì fún ìdílé rẹ̀ Ìpín Ti Ẹ̀yà Símíónì Gègé kéjì jáde fún ẹ̀yà Símíónì, ní agbo ilé, ní agbo ilé Ìní wọn sì wà ní àárin ilẹ̀ Júdà Lára ìpín wọn ní Béérí Ṣébà , Móládà, Hasari-Ṣúálì, Báláhì, Ésémù, Élítóládì, Bétúlì, Hómà, síkílágì, Bẹti-Mákábótì, Hasari-Súsà, Bẹti-Lébà ati Ṣárúẹ́nì, ìlú wọn jẹ́ mẹ́talá àti ìletò wọn Háínì, Rímónì, Étérì àti Áṣánì Ìlú wọn jẹ́ mẹ́rin àti ìletò wọn Àti gbogbo àwọn agbégbé ìlú wọ̀nyí títí dé Baalati-Béérì Èyí ni ìní àwọn ọmọ Símíónì, agbo ilé, ní agbo ilé A mú ogún ìní àwọn ọmọ Símíónì láti ìpín Júdà, nítorí ìpín Júdà pọ̀ ju èyí tí wọ́n nílò lọ Báyìí ni àwọn ọmọ Símíónì gba ìní wọn ní àárin ilẹ̀ Júdà Gègé kẹ́ta jáde fún Sébúlunì, ní agbo ilé ní agbo ilé Ààlà ìní wọn sì lọ títí dé Sárídì Ó sì lọ sí ìwọ̀-oòrùn ní Márálà, ó sì dé Dábésẹ́tì, ó sì lọ títí dé Ráfénì odo ní ẹ̀bá Jókíníámù Ó sì yípadà sí ìlà-oòrùn láti Sérídì sí ìhà ìlà-oòrùn dé ilẹ̀ Kisiloti-Tábórì, ó sì lọ sí Dábérátì, ó sì gòkè lọ sí Jáfíà Nígbà náà ní o lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Gati-Héférì àti Eti-Kásínì, ó sì jáde ní Rímónì, ó sì yí sí ìhà Níà Ní ibẹ̀, ààlà sì yí ká ní ìhà àríwá lọ sí Hánátónì ó sì pin ní Àfonífojì Ifita Élì Lára wọn ni Kátatì, Náhalálì, Símírónì, Ìdálà àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlá àti ìletò wọn Ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn jẹ́ ìní Sébúlunì, ní agbo ilé agbo ilé Gègé kẹrin jáde fún Ísákárì, agbo ilé ní agbo ilé Lára ilẹ̀ wọn ni èyí Jésíréélì, Késúlótì, Súnemù, Háfáráímù, Ṣíhónì, Ánáhárátì, Rábítì, Kíṣíónì, Ébésì, Rémétì, Ẹni-Gánnímù, Ẹni-Hádà àti Bẹ́tì-Pásésì Ààlà náà sì dé Tábórì, Ṣáhásúmà, àti Bẹti Ṣẹ́mẹ́ṣì, ó sì pin ní Jọ́dánì Wọ́n sì jẹ́ ìlú mẹ́rindínlógún àti iletò wọn Ìlú wọ̀nyí àti iletò wọn jẹ́ ìní ẹ̀yà Ísákárì, ní agbo ilé agbo ilé Gègé karùnún jáde fún ẹ̀yà Áṣíérì, ní agbo ilé agbo ilé Lára ilẹ̀ wọn ni èyí Hélíkátì, Hálì, Bẹ́tẹ́nì, Ákísáfù, Álàmélékì, Ámádì, àti Míṣálì Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ààlà náà dé Kámẹ́lì àti Ṣíhórì-Líbínátì Nígbà náà ni o yí sí ìhà ilà-oòrùn Bẹti-Dágónì, dé Sébúlúnì àti Àfonífojì Ífíta-Élì, ó sì lọ sí àríwá sí Bẹti-Ẹ́mẹ́kì àti Néíélì, ó sì kọjá lọ sí Kábúlì ní apá òsì Ó sì lọ sí Ábídónì, Réóbù, Hámónì àti Kánà títí dé Sídónì ńlá Ààlà náà sì tẹ̀ sí ìhà Rámà, ó sì lọ sí ìlú olódi Tirè, ó sì yà sí Hósà, ó sì jáde ní òkun ní ilẹ̀ Ákísíbì, Úmà, Áfẹ́kì àti Réóbù Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlélógún àti ìletò wọn Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Áṣíérì, ní agbo ilé agbo ilé Ìpín kẹfà jáde fún Náfítalì, agbo ilé ní agbo ilé Ààlà wọn lọ láti Hẹ́lẹ́fì àti igi ńlá ní Sááná nímù kọjá lọ sí Ádámì Nékébù àti Jábínẹ́ẹ́lì dé Lákúmì, ó sì pín ní Jọ́dánì Ààlà náà gba ìhà ìwọ̀-oòrùn lọ sí Ásínótì, Tabori ó sì jáde ní Húkókì Ó sì dé Sébúlúnìe ní ìhà gúsù, Ásíẹ́rì ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Jọ́dánì ní ìhà ìlà-oòrùn Àwọn ìlú olódi sì Sídímù, Sérì, Hámátì, Rákátì, Kínérétì, Ádámà, Rámà Hásórì, Kédéṣì, Édíréì, Ẹ́ní-Hásórì, Írónì, Mígídálì-Élì, Hórémù, Bẹ́tì-Ánátì àti Bẹ́tì-Sẹ́mẹ́ṣì Wọ́n sì jẹ́ ìlú mọ́kàndínlógún àti ìletò wọn Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Náfitalì, ní agbo ilé sí agbo ilé Ìbò keje jáde fún ẹ̀yà Dánì, ní agbo ilé ní agbo ilé Ilẹ̀ ìní wọn nì wọ̀nyí Sórà, Éṣtaólì, Írí-Ṣẹ́mẹ́sì, Ṣáálábínì, Áíjálónì, Ítílà, Élónì, Tímínà, Ékírónì, Élítékè, Gíbétónì, Báálátì, Jéúdì, Béné-Bérákì, Gátí-Rímónì, Mé Jákónì àti Rákónì, pẹ̀lú ilẹ̀ tí ó kọjú sí Jópà Àwọn ìlú wọ̀n yí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Dánì, ní agbo ilé agbo ilé Nígbà tí wọ́n ti parí pínpín ilẹ̀ náà ní ìpín ti olúkúlùkù, àwọn ará Ísírẹ́lì fún Jóṣúà ọmọ Núnì ní ìní ní àárin wọn Bí Olúwa ti pàṣẹ, wọ́n fún-ún ni ìlú tí ó béèrè fún—Tímínátì Sérà ní ìlú òkè Éfúráímù Ó sì kọ́ ìlú náà, ó sì ń gbé ibẹ̀ Wọ̀nyí ni àwọn ilẹ̀ tí Élíásárì àlùfáà, Jósúà ọmọ Núnì àti àwọn olórí ẹ̀yà agbo ilé Ísírẹ́lì fi ìbò pín ní Sílò ní iwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé Báyìí ni wọ́n parí pínpín ilẹ̀ náà Ráhábù Àti Àwọn Amí Nígbà náà ni Jóṣúà ọmọ Núnì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò méjì jáde ní àsírí láti Ṣítímù Ó sì wí pé, Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá Jẹ́ríkò Wọ́n sì lọ, wọ́n wọ ilé aṣẹ́wó kan, tí à ń pè ní Ráhábù, wọ́n sì dúró síbẹ̀ A sì sọ fún ọba Jẹ́ríkò, Wò ó! Àwọn ará Ísírẹ́lì kan wá ibí ní alẹ́ yìí láti wá yọ́ ilẹ̀ yí wò Ọba Jẹ́ríkò sì ránṣẹ́ sí Ráhábù pé Mú àwọn ọkùnrin nì tí ó tọ̀ ọ́ wá, tí ó wọ inú ilé rẹ jáde wá, nítorí wọ́n wá láti yọ́ gbogbo ilẹ̀ yìí wò ni Ṣùgbọ́n obìnrin náà ti mú àwọn ọkùnrin méjì náà, o sì fi wọ́n pamọ́ Ó sì wí pé, lóótọ́ ní àwọn ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ibi tí wọ́n ti wá Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, nígbà tí ó tó àkókò làti ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè, àwọn ọkùnrin náà sì jáde lọ Èmi kò sì mọ ọ̀nà tí wọ́n gbà lọ Ẹ lépa wọn kíákíá Ẹ̀yin yóò bá wọn Àwọn ọkùnrin náà jáde lọ láti lépa àwọn amí náà ní ọ̀nà tí ó lọ sí ìwọdò Jọ́dánì, bí àwọn tí ń lépa wọn sì ti jáde, wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè Kí àwọn ayọ́lẹ̀wò náà tó sùn ní alẹ́, ó gòkè tọ̀ wọ́n lọ lókè àjà Ó sì sọ fún wọn, Èmi mọ̀ pé Olúwa ti fún un yín ní ilẹ̀ yìí, àti pé ẹ̀rù u yín ti sọ wá di ojo dé ibi pé ìdí gbogbo àwọn tí ó n gbé ilẹ̀ yìí ti di omi nítorí iyín Àwa ti gbọ́ bí Olúwa ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú u yín nígbà tí ẹ̀yin jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí Ṣíhónì àti Ógù, àwọn ọba méjèèjì ti Ámórì ti ìlà-oòrùn Jọ́dánì, tí ẹ̀yin parun pátapáta Bí a ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí ọkàn an wa pámi, kò sì sí okun kankan fún wa mọ́ nítorí i yín, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti ní ayé Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ búra fún mi ní ti Olúwa pé ẹ̀yin yóò ṣe àánú fún ìdílé mi, nítorí pé mo ti ṣe yín ní oore Ẹ fún mi ní àmì tó dájú pé ẹ̀yin yóò dá ẹ̀mí baba àti ìyá mi sí arákùnrin mi àti arábinrin mi, àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, àti pé ẹ̀yin yóò gbà wá là lọ́wọ́ ikú Ẹ̀mí wa fún ẹ̀mí in yín! àwọn ọkùnrin náà mú dá a lójú Tí ìwọ kò bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò sì fi òtítọ́ àti àánú bá ọ lò nígbà tí Olúwa bá fún wa ní ilẹ̀ náà Nígbà náà ní ó fi okùn sọ̀ wọ́n kalẹ̀ ní ojú u fèrèsé, nítorí ilé tí ó ń gbé wà ní ara odi ìlú Ó sì ti ṣọ fún wọn pé, Ẹ lọ sí orí òkè, kí ẹ sì fi ara pamọ́ níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta kí àwọn tí ń lépa yín má baà rí i yín títí tí wọn yóò fi darí Lẹ́yìn náà kí ẹ máa bá ọ̀nà yín lọ Àwọn arákùnrin náà sì sọ fún un pé, Kí ọrùn un wa baà lè mọ́ kúró nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú yìí Nígbà tí àwa bá wọ ilé è rẹ, ìwọ yóò ṣo okùn aláwọ̀ aró yìí sí ojú fèrèsé èyí tí ìwọ fi sọ̀ wá kalẹ̀, kí ìwọ kí ó mú baba rẹ, ìyá rẹ, àwọn arákùnrin in rẹ àti gbogbo ìdílé è rẹ kí wọ́n wá sí inú ilé è rẹ Bí ẹnikẹ́ni bá jáde sí ìta láti inú ilé è rẹ sí inú ìgboro ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò sì wà ní orí ara rẹ̀ ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí i rẹ̀ Fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ilé pẹ̀lú ù rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní órí i wa bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kàn án Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá sọ ohun tí àwá ń se, àwa yóò bọ́ nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú Ó dáhùn pé, Ó dára bẹ́ẹ̀  Ẹ jẹ́ kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí ṣọ Ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì lọ Ó sì so okùn òdòdó náà sí ojú u-fèrèsé Nígbà tí wọ́n kúrò, wọ́n sì lọ sí orí òkè, wọ́n sì dúró ní ibẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́ta, títí àwọn alépa fi wá wọn ní gbogbo ọ̀nà wọ́n sì padà láìrí wọn Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin méjì náà padà Wọ́n sì ṣọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, wọ odò, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Jóṣúà ọmọ Núnì wọ́n sì sọ fún un gbogbo ohun tí ó ti sẹlẹ̀ sí wọn Wọ́n sì sọ fún Jóṣúà, Nítòótọ́ ni Olúwa tí fi gbogbo ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́ gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà ni ìbẹ̀rù-bojo ti mú nítorí i wa Àwọn Ìlú Ààbò Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Jósúà pé, Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọn yan àwọn ìlú ààbò, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún ọ láti ẹnu Mósè, kí ẹni tí ó bá sèèsì pa ènìyàn tàbí tí ó bá pa ènìyàn láìmọ̀ọ́mọ̀ lè sálọ sí ibẹ̀, fún ààbò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa Nígbà tí ó bá sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, yóò sì dúró ní ẹnu ọ̀nà àtiwọ ibodè ìlú, kí ó sì ṣe àlàyé ara rẹ̀ ní iwájú àwọn àgbààgbà ìlú náà Nígbà náà ni wọn yóò gbà á sí ìlú wọn, wọn yóò sì fun ní ibùgbé láàárin wọn Bí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ bá ń lépa wọn, wọn kò gbọdọ̀ fi àwọn ọ̀daràn náà lé wọn lọ́wọ́, nítorí Òun ó sì máa gbé inú ìlú náà, títí yóò fi jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn àti títí ikú olórí àlùfáà tí ó ń siṣẹ́ ìsìn nígbà náà Nígbà náà ó lè padà sí ilé rẹ̀ ní ìlú tí ó ti sá wá Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan Kedésì ní Gálílì ní ìlú òkè Náfítanì, Sékémù ní ìlú òkè Éfúráímù, àti Kíríátì aginjù ní ìlú òkè Júdà Ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì ti Jẹ́ríkò, wọ́n ya Bésẹ́rìù ní aṣalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Rámótì ní Gílíádì ní ẹ̀yà Gádì, àti Golanì ní Básánì ní ẹ̀yà Mánásè Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàbí àlejò tí ń gbé ní àárin wọn tí ó sèèsì pa ẹnìkan lè sálọ sí àwọn ìlú tí a yà sọ́tọ̀ wọ̀nyí, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má sì ṣe pa á kí ó to di àkókò tí yóò jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn Àwọn Ìlú Àwọn Ọmọ Léfì Báyìí ni olórí ìdílé àwọn ọmọ Léfì lọ bá Élíásárì àlùfáà, Jóṣúà ọmọ Núnì àti olórí ẹ̀yà àwọn ìdílé ẹ̀yà Ísírẹ́lì Ní Sílò, ní Kénánì, wọn sọ fún wọn pé, Olúwa pàṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé kí wọn fún wa ní ìlú láti máa gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn wa Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú wọ̀nyí, àti ilẹ̀ pápá oko tútù lára ilẹ̀ ìní ti wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Ìpín kìn-ín-ni wà fún àwọn ọmọ Kóhátì, ní agbo ilé, agbo ilé Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Árónì àlùfáà ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara Símónì àti Bẹ́ńjámínì Ìyòókù àwọn ọmọ Kóhátì ni a pín ìlú mẹ́wàá fún láti ara ẹ̀yà Éfúráímù, Dánì àti ìdajì Mánásè Àwọn ẹ̀yà Gásónì ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara ẹ̀yà Ísákárì, Áṣíérì, Náfitalì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè ní Básánì Àwọn ọmọ Mérárì ní agbo ilé, agbo ilé ni wọ́n fún ní ìlú méjìlá láti ara ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti Sébúlónì Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pín ìlú wọ̀nyí àti ilẹ̀ pápá oko tutù fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Móse Láti ara ẹ̀yà Júdà àti ẹ̀yà Síméónì ni wọ́n ti pín àwọn ìlú tí a dárúkọ wọ̀nyí, Wọ́n fún wọn ní Kiriati Áríbà , pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù tí ó yí wọn ká, ní ilẹ̀ òkè Júdà Ṣùgbọ́n àwọn oko àti àwọn abúlé ní agbégbé ìlú náà ni wọ́n ti fi fún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀ Ní àfikún wọ́n sì fún àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ní Hébúrónì pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù rẹ̀, Líbínà, Játírì, Ésítẹ́móà, Hólónì àti Débírì, Háínì, Jútà àti Bẹti-Sẹ́mẹ́sì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn Ìlú mẹ́sàn án láti ara ẹ̀yà méjì wọ̀nyí Láti ara ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni wọ́n ti fún wọn ní Gíbíónì, Gẹ́bà, Ánatótì àti Álímónì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin Gbogbo ìlú àwọn àlùfáà, ìran Árónì, jẹ́ mẹ́talá, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá wọn Ìyòókù ìdílé Kóhátì tí ó jẹ́ ọmọ Léfì ní a pín ìlú fún láti ara ẹ̀yà Éfúráímù Ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù wọ́n fún wọn ní Ṣẹ́kẹ́mù ati Gésérì, Kíbásáímù àti Bẹti-Hórónì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin Láti ara ẹ̀yà Dánì ní wọ́n ti fún wọn ní Élítékè Gíbátónì, Áíjálónìd àti Gati-Rímónì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn jẹ́ mẹ́rin Láti ara ìdajì ẹ̀yà Mánásè ní wọ́n ti fún wọn ní Tánákì àti Gati-Rímónì pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú méjì Gbogbo ìlú mẹ́wẹ̀wá yìí àti ilẹ̀ pápá wọn ni a fi fún ìyókù ìdílé Kóhátì Àwọn ọmọ Gáṣóní idile àwọn ọmọ Lefi ní wọ́n fún lára ìdajì ẹ̀yà Mánásè, Gólánì ní Básánì àti Be Ésítarà pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn jẹ́ méjì Láti ara ẹ̀yà Ísákárì ni wọ́n ti fún wọn ní, Kísíónì Dábérátì, Járímútì àti Ẹni Gánímù, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ mẹ́rin Láti ara ẹ̀yà Ásíérì ni wọ́n ti fún wọn ní Mísálì, àti Ábídónì, Hélíkátì àti Réhóbì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ mẹ́rin Láti ara ẹ̀yà Náfítanì ni a ti fún wọn ní Kedeṣì ní Gálílì , Hámótì Dórì àti Kárítanì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́ta Gbogbo ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Gáṣónì jẹ́ mẹ́talá, pẹ̀lú ilẹ́ pápá oko wọn Láti ara ẹ̀yà Sébúlónì ni a ti fún ìdílé Mérárì ní Jókíníámù, Kárítà, Dímínà àti Náhálálì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin Láti ara ẹ̀yà Rúbẹ́nì ni wọ́n ti fún wọn ní Bésérì, àti Jáhásì, Kédémótì àti Mẹ́fátì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ mẹ́rin Láti ara ẹ̀yà Gádì ní wọ́n ti fún wọn ní Rámótìa ní Gílíádì , Máhánáímù, Hésíbónì àti Jásérì, e pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin Gbogbo ìlú tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Mérárì tí wọ́n jẹ́ ìyókù àwọn ọmọ Léfì jẹ́ méjìlá Gbogbo ìlú àwọn ọmọ Léfì tó wà láàárin ara ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ méjìdínláádọ́ta lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko wọn Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìlú wọ̀nyí ni ó ni ilẹ̀ pápá oko tí ó yí ì ká, bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún gbogbo ìlú wọ̀nyí Báyìí ni Olúwa fún Ísírẹ́lì ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí láti fi àwọn fún baba ńlá wọn Nígbà tí wọ́n sì gbà á tan wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀ Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí ó ti sèlèrí fún baba ńlá wọn Kò sì sí ọ̀kankan nínú àwọn ọ̀ta wọn tí ó lè dojú kọ wọ́n Olúwa sì fi gbogbo àwọn ọ̀ta wọn lé wọn ní ọwọ́ Kò sí ọ̀kan nínú ìlérí rere tí ó se fún ilé Ísírẹ́lì tí ó kùnà Gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe Àwọn Ẹ̀yà Ti Ìlà-Oòrùn Padà Sí Ilẹ̀ Ìní Wọn Jóṣúà sì pe àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè ó sì sọ fún wọn pé, Ẹ̀yin ti ṣe gbogbo èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa pàṣẹ, ẹ sì ti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun gbogbo tí mo pàṣẹ Ẹ kò fi àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ láti ìgbà yí títí di òní, ṣùgbọ́n ẹ ti kíyèsára láti pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́ Nísinsìn yìí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí, ẹ padà sí ilẹ̀ yín níbi tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin ní òdì kéjì Jọ́dánì Ṣùgbọ́n ẹ sọ́ra gidigidi láti pa àṣẹ àti òfin tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin mọ́ Láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, láti rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti gbọ́ràn sí àṣẹ rẹ̀, láti dì í mú ṣinṣin àti láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà yín Nígbà náà ni Jóṣúà súre fún wọn, ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn Jóṣúà súre fún wọn ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn, Ó sì wí pé, Ẹ padà sí ilẹ̀ ẹ yín pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀ yín, pẹ̀lú agbo ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú fàdákà, wúrà, idẹ àti irin, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ, kí ẹ sì pín ìkógún tí ẹ rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ta yín pẹ̀lú àwọn arákùnrin yín Báyìí ni àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè fi àwọn ará Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní Sílò ní Kénánì láti padà sí Gílíádì, ilẹ̀ wọn, èyí tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè wá Nígbà tí wọ́n wá dé Gélílótì ní ẹ̀bá Jọ́dánì ní ilẹ̀ Kénánì, àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè mọ pẹpẹ ńlá tí ó tóbi kan ní ẹ̀bá Jọ́dánì Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti mọ pẹpẹ ní orí ààlà Kénánì ní Gélíótì ní ẹ̀bá Jọ́dánì ní ìhà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gbogbo àjọ Ísírẹ́lì péjọ ní Ṣílò láti lọ bá wọn jagun Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rán Fínéhásì ọmọ Élíásárì àlùfáà, sí ilẹ̀ Gílíádì, sí Rúbẹ́nì, sí Gádì àti sí ìdajì ẹ̀yà Mánásè Pẹ̀lú rẹ̀ wọ́n rán àwọn ọkùnrin olóyè mẹ́wàá, ẹnìkan fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, olórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ti wọn jẹ́ olórí ìdílé láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Nígbà tí wọ́n lọ sí Gílíádì-sí Rúbẹ́nì, Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè wọ́n sì sọ fún wọn pé, Gbogbo àjọ ènìyàn Olúwa wí pe A fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi sẹ̀ sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì nípa yíyí padà kúró lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ẹ sì kọ́ pẹpẹ ìsọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Olúwa Ẹ̀sẹ̀ Péórì kò ha tó fún wa bí Títí di òní yìí àwa kò tíì wẹ ara wa mọ́ kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀-àrùn ti jà láàárin ènìyàn Olúwa ! Ṣé ẹ tún wá ń padà kúrò lẹ́yìn Olúwa ni báyìí  Tí ẹ̀yin bá sọ̀tẹ̀ sí Olúwa ní òní, ní ọ̀la ní òun o bínú sí gbogbo ìpéjọpọ̀ Ísírẹ́lì Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní Olúwa , ní ibi tí àgọ́ Olúwa dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe sọ̀tẹ̀ sí Olúwa tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa Nígbà tí Ákánì ọmọ Sérà ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọtọ̀, ǹjẹ́ ìbínú kò wá sí orí gbogbo àjọ ènìyàn Ísírẹ́lì nítorí rẹ̀ bí Òun nìkan kọ́ ni ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀   Nígbà náà ni Rúbénì, Gádì àti ẹ̀yà Mánásè sọ nínú ìdáhùn wọn fún àwọn olórí Ísírẹ́lì pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run! Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run, Òun mọ̀ jẹ́ kí Ísírẹ́lì kí ó mọ̀! Bí èyí bá wà ní ìsọ̀tẹ̀ tàbí àìgbọ́ràn sí Olúwa , ẹ má ṣe dá wa sí ní òní yìí Bí àwa bá ti mọ pẹpẹ wa láti yí padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa àti láti rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ jíjẹ, tàbí ẹbọ àlàáfíà ní orí rẹ, kí Olúwa fún ara rẹ̀ gba ẹ̀san Bẹ́ẹ̀ kọ́! Àwa ṣe èyí ní ìbẹ̀rù pé ní ọjọ́ tí àwọn ọmọ yín yóò wí fún wa pé, Kí ni ẹ̀yín ní ṣe pẹ̀lú Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì Olúwa ti fi Jódánì ṣe ààlà láàárin àwa àti ẹ̀yin-àwọn ọmọ Réúbénì àti àwọn ọmọ Gádì! Ẹ kò ni ní ìpín nínú Olúwa Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ yín lè mú kí àwọn ọmọ wa dẹ́kun láti máa bẹ̀rù Olúwa Nítorí èyí ni àwa ṣe wí pé, Ẹ jẹ́ kí àwa múra láti mọ pẹpẹ kan, Ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ọrẹ sísun, tàbí fún àwọn ìrúbọ Ní ọ̀nà mìíràn, yóò jẹ́ ẹ̀rí kan láàárin àwa àti ẹ̀yin àti àwọn ìran tí ń bọ̀, pé àwa yóò jọ́sìn fún Olúwa ní ibi mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ sísun wa, ẹbọ àti ọrẹ àlàáfíà Nígbà náà ni ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín kò ní lè sọ fún tiwa pé, Ẹ kò ní ìpín nínú ti Olúwa Àwa sì wí pé, Tí wọ́n bá tilẹ̀ sọ èyí fún wa, tàbí sí àwọn ọmọ wa, a ó dáhùn pé Ẹ wo àpẹrẹ pẹpẹ Olúwa , èyí tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ọrẹ sísun àti ẹbọ ṣùgbọ́n fún ẹ̀rí láàrin àwa àti ẹ̀yin Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí àwa kí ó ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa , kí àwa sì yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ ní òní nípa mímọ pẹpẹ fún ẹbọ sísun ọrẹ oúnjẹ jíjẹ àti ẹbọ lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa tí ó dúró níwájú àgọ́ rẹ̀ Nígbà tí Fínéhásì àlùfáà àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn, àwọn olórí ìdílé Ísírẹ́lì gbọ́ ohun tí Réúbẹ́nì, Gádì àti Mánásè ti sọ, ó dùn mọ́ wọn Fínéhásì ọmọ Élieásárì, àlùfáà wí fún Réúbẹ́nì, Gádì àti Mánásè, Ní òní ni àwa mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú wa, nítorí tí ẹ̀yin kò hùwà àìṣòtítọ́ sí Olúwa ní orí ọ̀rọ̀ yí nísinsin yìí, ẹ̀yin ti yọ àwọn ará Ísírẹ́ì kúrò ní ọwọ́ Olúwa Nígbà náà ni Fínéhásì ọmọ Élíásárì àlùfáà àti àwọn olórí padà sí Kénánì láti ibi ìpàdé wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Réúbẹ́nì àti ẹ̀yà Gádì ní Gílíádì, wọ́n sì mú ìròyìn tọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ Inú wọn sì dùn láti gbọ́ ìròyìn náà, wọ́n sì yin Ọlọ́run Wọn kò sì sọ̀rọ̀ mọ́ nípa lílọ bá wọn jagun láti run ilẹ̀ tí àwọn ẹ̀yà Réúbẹ́nì àti ẹ̀yà Gádì ń gbé Ẹ̀yà Réúbẹ́nì àti ẹ̀yà Gádì sì fún pẹpẹ náà ní orúkọ yìí Ẹ̀rí láàárin wa pé Olúwa ni Ọlọ́run Ọ̀rọ̀ Ìdágbére Jóṣúà Sí Àwọn Olórí Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, nígbà tí Olúwa sì ti fún Ísírẹ́lì ní ìsinmi kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká nígbà náà Jóṣúà sì ti di arúgbó Ó sì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ àgbààgbà wọn, olórí wọn, adájọ́ àti àwọn ìjòyè, ó sì sọ fún wọn pé, Èmi ti pọ̀ ní ọdún èmi ti di arúgbó Ẹ̀yin tìkára yín sì ti rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí gbogbo orílẹ̀ èdè wọ̀nyí nítorí yín, Olúwa Ọlọ́run yín ni ó jà fún yín Ẹ rántí bí mo ṣe pín ogún ìní fún àwọn ẹ̀yà yín ní ilẹ̀ orílẹ̀ èdè gbogbo tí ó kù àwọn orílẹ̀ èdè tí mo ti sẹ́gun-ní àárin Jọ́dánì àti Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn Olúwa Ọlọ́run yín fúnra rẹ̀ yóò lé wọn jáde kúrò ní ọ̀nà yín, yóò sì tì wọ́n jáde ní iwájú yín, ẹ̀yin yóò sì gba ilẹ̀-ìní wọn, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún yín Ẹ jẹ́ alágbára gidigidi, kí ẹ sì sọ́ra láti ṣe ìgbọ́ran sí ohun tí a kọ sí inú Ìwé Ofin Mósè, láìyí padà sí ọ̀tún tàbí sí òsì Ẹ má ṣe ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè tí ó sẹ́kù láàárin yín ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà wọn tàbí kí ẹ fi wọ́n búra Ẹ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tàbí ki ẹ tẹríba fún wọn Ṣùgbọ́n ẹ di Olúwa Ọlọ́run yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń se tẹ́lẹ̀ títí di àkókò yìí Olúwa ti lé àwọn orílẹ̀ èdè ńlá àti alágbára kúrò níwájú yín títí di òní yìí kò sí ẹnìkan tí ó le dojú kọ yín Ọ̀kan nínú yín lé ẹgbẹ̀rún ọ̀ta, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín jà fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ sọ́ra gidigidi láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín Ṣùgbọ́n bí ẹ bá yí padà, tí ẹ sì gba ìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó sẹ́kù lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù láàárin yín, tí ẹ sì ń fọmọ fún ara yín ní ìyàwó, tí ẹ sì bá wọn ní àjọṣepọ̀, Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé Olúwa Ọlọ́run yín kì yóò lé àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí jáde mọ́ kúrò níwájú yín Dípò èyí, wọn yóò jẹ́ ìkẹkùn àti tàkúté fún un yín, pàsán ní ẹ̀yin yín àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ ó fi ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ dáradára yí, èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fi fún yín Nísinsin yìí èmi ti fẹ́ máa lọ sí ibi tí àwọn àgbà ń rè Ẹ mọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti àyà yín pé, kò sí ohun kan tí ó kùnà nínú àwọn ìlérí rere gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín Gbogbo ìlérí tó ti se kò sí ọ̀kan tí ó kùnà Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí dáradára gbogbo ti Olúwa Ọlọ́run yín ti wá sí ìmúsẹ, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò mú ibi gbogbo tí ó ti kìlọ̀ wá sí orí yín, títí yóò fi pa yín run kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín Bí ẹ bá sẹ̀ sí májẹ̀mu Olúwa Ọlọ́run yín, èyí tí ó pàṣẹ fún un yín, tí ẹ bá sì lọ tí ẹ sì sin àwọn òrìṣà tí ẹ sì tẹ orí ba fún wọn, ìbínú gbígbóná Olúwa yóò wá sórí i yín, ẹ̀yin yóò sì ṣègbé kíákíá kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín Májẹ̀mu Di Ọ̀tun Ní Sékémù Nígbà náà ni Jóṣúà pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì jọ ní Ṣékémù Ó pe àwọn àgbààgbà, àwọn olórí, onídájọ́ àti àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run Jóṣúà sì sọ fun gbogbo ènìyàn pé, Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí Nígbà kan rí àwọn baba ńlá yín Térà bàbá Ábúráhámù àti Náhórì ń gbé ní ìkọjá odò, wọ́n sì sin àwọn òrìṣà Ṣùgbọ́n mo mú Ábúráhámù baba yín kúrò ní ìkọjá odò mo sì ṣe amọ̀nà rẹ̀ ni gbogbo Kénánì, mo sì fún ní àwọn ọmọ púpọ̀ Mo fún ní Ísáákì, Èmi sì fún ní Ísáákì, mo fún ní Jákọ́bù àti Ísáù, mo sì fún Ísáù ní ilẹ̀ orí òkè Séírì, Ṣùgbọ́n Jákọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì  Nígbà náà ni mo rán Mósè àti Árónì, mo sì yọ Éjíbítì lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Éjíbítì, ẹ wá sí òkun, àwọn ará Éjíbítì lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun pupa Ṣùgbọ́n wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, ó sì fi òkùnkùn sí àárin yín àti àwọn ará Éjíbítì, ó sì mú òkun wá sí orí i wọn ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ Ẹ sì fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Éjíbítì Lẹ́yìn náà ẹ sì gbé ní ihà fún ọjọ́ pípẹ́  Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Ámórì tí ó ń gbé ìlà-oòrùn Jọ́dánì Wọ́n bá yín jà, Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́ Èmí pa wọ́n run kúrò ní wájú u yín, ẹ sì gba ilẹ̀ ẹ wọn Nígbà tí Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù, múra láti bá Ísírẹ́lì jà, ó ránṣẹ́ sí Bálámù ọmọ Béóríù láti fi yín bú Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Bálámù, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín ṣíwájú àti ṣíwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀  Lẹ́yìn náà ni ẹ ré kọjá Jọ́dánì, tí ẹ sì wá sí Jẹ́ríkò Àwọn ará ìlú Jẹ́ríkò sì bá yín jà, gẹ́gẹ́ bí ará Ámórì, Pérísì, Kénánì, Hítì, Gígásì, Hífì àti Jébúsì Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́ Èmi sì rán oyin sí iwájú yín, tí ó lé wọn kúrò ní iwájú yín, àní ọbá Ámórì méjì Ẹ kò ṣe èyí pẹ̀lú idà yín àti ọrun yín Bẹ́ẹ̀ ni mo fún un yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò ṣiṣẹ́ fún, àti àwọn ìlú tí ẹ̀ yin kò kọ́ ẹ sì ń gbé inú wọn, ẹ sì ń jẹ nínú ọgbà àjàrà àti ọgbà ólífì tí ẹ kò gbìn Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù Olúwa , kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò àti ní Éjíbítì kúrò, kí ẹ sì máa sin Olúwa Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fẹ́ láti sin Olúwa nígbà náà ẹ yàn fún ara yín ní òní ẹni tí ẹ̀yin yóò sìn bóyá òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò, tàbí òrìṣà àwọn ará Ámórì, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé Ṣùgbọ́n ní ti èmi àti ilé mi, Olúwa ni àwa yóò máa sìn Àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, Kí a má ri tí àwa yóò fi kọ Olúwa sílẹ̀ láti sin òrìṣà ! Nítorí Olúwa Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni ó gba àwọn baba ńlá wa là kúrò ní Éjíbítì, ní oko ẹrú Òun ni Ọlọ́run tí ó ṣe ìyanu ńlá níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ó pa wá mọ́ nínú gbogbo ìrìnàjò wa àti ní àárin gbogbo orílẹ̀ èdè tí a là kọjá Olúwa sì lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè jáde kúrò ní iwájú wa, pẹ̀lú àwọn Ámórì, tí ń gbé ilẹ̀ náà Àwa náà yóò máa sin Olúwa , nítorí òun ni Ọlọ́run wa Jóṣúà sì wí fún àwọn ènìyàn náà, pé, Ẹ̀yin kò le sin Olúwa , nítorí Ọlọ́run mímọ́ ni òun Ọlọ́run owú ni òun, Kì yóò dárí ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín Bí ẹ bá kọ Olúwa tí ẹ sì sin òrìṣà orílẹ̀ èdè mìíràn òun yóò padà yóò sì mú ibi bá a yín, yóò sì pa yín run, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣe rere fún un yín tan Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ fún Jóṣúà pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́! A yàn láti sin Olúwa Lẹ́yìn náà ni Jóṣúà wí pé, Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín pé, ẹ ti yàn láti sin Olúwa Wọ́n dáhùn wí pé, Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí Nígbà náà ni Jóṣúà dáhùn wí pé, Ẹ mú òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn tí ń bẹ ní àárin yín kúrò, ki ẹ sì yí ọkàn yín padà sí Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì Àwọn ènìyàn náà sì wí fún Jóṣúà pé, Olúwa Ọlọ́run nìkan ni àwa yóò máa sìn, òun nìkan ni àwa yóò máa ṣe ìgbọràn sí Ní ọjọ́ náà Jóṣúà dá májẹ̀mu fún àwọn ènìyàn, ó sì fi òfin àti ìlànà fún wọn ní Sékémù Jóṣúà sì kọ gbogbo ìdàhùn àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí inú Ìwé Òfin Ọlọ́run Lẹ́yìn náà ó gbé òkúta ńlá kan, ó gbé e kalẹ̀ ní abẹ́ igi Óákù ní ẹ̀bá ibi-mímọ́ Olúwa E wò ó! ó wí fún gbogbo ènìyàn pé, Òkúta yìí ni yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún wa, nítorí ó ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ fún wa Yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí yín tí ẹ bá ṣe àìṣòtítọ́ sí Ọlọ́run yín Lẹ́yìn náà ni Jóṣúà jẹ́ kí àwọn ènìyàn lọ, olúkúlùkù sí ilẹ̀-ìní rẹ̀, Lẹ́yìn nǹkàn wọ̀nyí, Jóṣúà ọmọ Núnì ìránṣẹ́ Olúwa , kú ní ẹni àádọ́fà ọdún Wọ́n sì sin ín sí ilẹ̀ ìní rẹ̀, ní Tíminátì Sérà ni ilẹ̀ orí òkè Éfúráímù, ní ìhà àríwá Òkè Gááṣì Ísírẹ́lì sì sin Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbààgbà tí ó pẹ́ ju Jóṣúà lọ àti àwọn tó ti rí ohun gbogbo tí Olúwa ti ṣe fún Ísírẹ́lì Egungun Jóṣéfù, èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó kúrò ní Éjíbítì, ni wọ́n sin ní Ṣékémù ní ìpín ilẹ̀ tí Jákọ́bù rà fún ọgọ́ọ̀rún fàdákà ní ọwọ́ Hámórì, baba Ṣékémù Èyí sì jẹ́ ilẹ̀-ìní àwọn ọmọ Jósẹ́fù Élíásérì ọmọ Árónì sì kú, wọ́n sì sin ín ní Gíbéà, tí a ti pín fún ọmọ rẹ̀ Fínéhásì ní òkè ilẹ̀ Éfúráímù Ísírẹ́lì Kọjá Nínú Odò Jọ́dánì Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, Jóṣúà ati gbogbo àwọn Ísírẹ́lì sí kúrò ní Sítímù, wọ́n sì lọ sí etí odò Jọ́dánì, wọ́n sì pa ibùdó síbẹ̀ kí wọn tó kọjá Lẹ́yìn ọjọ́ kẹ́ta àwọn olórí la àárin ibùdó já Wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé Nígbà tí ẹ bá rí àpótí i májẹ̀mú Olúwa , Ọlọ́run yín, tí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì rù ú, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sí kúrò ní ipò o yín, ẹ̀yin yóò sì máa tẹ̀lé e Ẹyin yóò lè mọ ọ̀nà tí ẹ ó gbà, torí pé ẹ̀yin kò gba ọ̀nà yìí tẹ́lẹ̀ rí Ṣùgbọ́n àlàfo gbọdọ̀ wà ní àárin yín àti àpótí náà, tó bí ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún un mítà Jóṣúà sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, Ẹ ya ara yín sí mímọ́, nítorí ní ọ̀la, Olúwa yóò ṣe ohun ìyanu ní àárin yín Jóṣúà sọ fún àwọn àlùfáà pé, Ẹ̀yin, ẹ gbé àpótí ẹ̀rí náà, kí ẹ̀yin kí ó sì máa lọ ṣáájú àwọn ènìyàn Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé e sókè, wọ́n sì ń lọ ní iwájú u wọn Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé, Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Ísírẹ́lì kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lúù rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Móṣè Sọ fún àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà Nígbà tí ẹ bá dé etí omi Jọ́dánì, ẹ lọ kí ẹ sì dúró nínú odò náà   Jóṣúà sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, Ẹ súnmọ́ ibí, kí ẹ̀yin kí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín Èyí ni ẹ̀yin yóò fi mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè wà ní àárin yín àti pé dájúdájú yóò lé àwọn ará Kénánì, àwọn ará Hítì, Hífì, Pérésì, Gágáṣì, Ámórì àti Jébúsì jáde níwájú u yín Àpótí ẹ̀rí Olúwa gbogbo ayé, ń gòkè lọ sí Jọ́dánì ṣáájú u yín Ǹjẹ́ nísinsìn yí, ẹ mú ọkùnrin méjìlá nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan Bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí Olúwa , Olúwa gbogbo ayé bá ti ẹṣẹ̀ bọ odò Jọ́dánì, omi tí ń ti òkè sàn wá yóò gé kúrò yóò sì gbájọ bí òkítì kan Nígbà tí àwọn ènìyàn gbéra láti ibùdó láti kọjá nínú odò Jọ́dánì, àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà ń lọ níwájú wọn Odò Jọ́dánì sì máa ń wà ní kíkún ní gbogbo ìgbà ìkórè Ṣùgbọ́n bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí ti dé odò Jọ́dánì, tí ẹṣẹ̀ wọn sì kan etí omi, omi tí ń ti òkè sàn wá dúró Ó sì gbájọ bí òkítì ní òkèèrè, ní ìlú tí a ń pè ní Ádámù, tí ó wà ní tòsí Sárétanì nígbà tí omi tí ń ṣàn lọ sínú òkun aginjù, gé kúrò pátapáta Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kọjá sí òdì kejì ní ìdojúkọ Jẹ́ríkò Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí Olúwa sì dúró ṣinṣin lórí ilẹ̀ gbígbẹ ní àárin Jọ́dánì, nígbà tí gbógbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kọjá títí gbogbo orílẹ̀ èdè náà fi ré kọjá nínú odò Jọ́dánì lórí ilẹ̀ gbígbẹ Nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọjá nínú odò Jọ́dánì tan, Olúwa ṣọ fún Jóṣúà pé, Yan ọkùnrin méjìlá nínú àwọn ènìyàn, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kí o sì pàṣẹ fún wọn pé Ẹ gbé òkúta méjìlá láti àárin odò Jọ́dánì ní ibi tí àwọn àlùfáà dúró sí, kí ẹ sì rù wọn kọjá, kí ẹ sì gbé wọn sí ibi tí ẹ̀yin yóò sùn ní alẹ́ yìí Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà pe àwọn ọkùnrin méjìlá tí ó ti yàn nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kàn, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ kọjá lọ ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín sí àárin odò Jọ́dánì Kí olúkúlùkù yín gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká a rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí ó sì jẹ́ àmì láàrin yín Ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ ọ yín pé, Kí ni òkúta wọ̀nyí dúró fún Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jọ́dánì kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Nígbà tí a rékọjá a Jọ́dánì, a gé omi Jọ́dáni kúrò Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láéláé Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bí Jóṣúà ti paláṣẹ fún wọn Wọ́n gbé òkúta méjìlá láti àárin odò Jọ́dánì gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bí Olúwa ti sọ fún Jóṣúà wọ́n sì rù wọ́n kọjá lọ sí ibùdó, ní ibi tí wọ́n ti gbé wọn kalẹ̀ Jóṣúà sì to òkúta méjìlá náà sí àárin odò Jọ́dánì fún ìrántí ní ọ̀kánkán ibi tí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí dúró sí Wọ́n sì wà níbẹ̀ di òní yìí Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí náà dúró ní àárin Jọ́dánì títí gbogbo nǹkan tí Olúwa pa láṣẹ Jóṣúà di síṣe ní paṣẹ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti pàṣẹ fún Jóṣúà Àwọn ènìyàn náà sì yára kọjá, bí gbogbo wọn sì ti rékọjá tán, ni àpótí ẹ̀rí Olúwa àti àwọn àlùfáà wá sí òdì kejì Bí àwọn ènìyàn sì ti ń wò wọ́n Àwọn ọkùnrin Rúbẹ́nì, Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mànásè náà sì rékọjá ní ìhámọ́ra ogun níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti pàṣẹ fún wọn Àwọn bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì tó ti múra fún ogun rékọjá lọ ní iwájú Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò láti jagun Ní ọjọ́ náà ni Olúwa gbé Jóṣúà ga ní ojú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì bẹ̀rù u rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé e wọn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti bẹ̀rù Móṣè Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé, Pàṣẹ fún àwọn àlùfáà tí o ń ru àpótí ẹ̀rí, kí wọn kí ó jáde kúrò nínú odò Jọ́dánì Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà pàṣẹ fún àwọn àlùfáà pé, Ẹ jáde kúrò nínú odò Jọ́dánì Àwọn àlùfáà náà jáde láti inú odò pẹ̀lú apòtí ẹ̀rí ni orí wọn Bí wọ́n ti fi ẹṣẹ̀ ẹ wọn tẹ orí ilẹ̀ gbígbẹ ni omi Jọ́dánì náà padà sí àyè e rẹ̀, o sì kún wọ bèbè bí i ti àtẹ̀yìn wá Ní ọjọ́ kẹwàá osù kìn-ní-ní àwọn ènìyàn náà lọ láti Jọ́dánì, wọ́n sì dúró ní Gílígálì ní ìlà-oòrùn Jẹ́ríkò Jóṣúà sì to àwọn òkúta méjìlá tí wọ́n mú jáde ní Jọ́dánì jọ ní Gílígálì Ó sì sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, Kí ni òkúta wọ̀nyí yìí dúró fún Nígbà náà ni ẹ ó jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé, Ísírẹ́lì rékọjá odò Jọ́dánì ní orí ilẹ̀ gbígbẹ Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín mú Jọ́dánì gbẹ ní iwájú u yín títí ẹ̀yin fi kọjá Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí Jọ́dánì gẹ́gẹ́ bí ó ti se sí Òkun Pupa, nígbà tí ó mú un gbẹ ní iwájú wa títí àwa fi kọjá Ó ṣe èyí kí gbogbo ayé lè mọ̀ pé ọwọ́ Olúwa ní agbára, àti kí ẹ̀yin kí ó lè máa bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín ní ìgbà gbogbo Ìkọlà Fún Ìran Tuntun Ísírẹ́lì Ìkọlà Ní Gílígálì Nígbà tí gbogbo àwọn ọba Ámórì ti ìlà-oòrùn Jọ́dánì àti gbogbo àwọn ọba Kénánì tí ń bẹ létí òkun gbọ́ bí Olúwa ti mú Jọ́dánì gbẹ ní iwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí ti a fi kọjá, ọkàn wọn pámi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ìgboyà mọ́ láti dojú kọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Nígbà náà ni Olúwa wí fún Jóṣúà pé, Fi akọ òkúta ṣe abẹ kí o sì kọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilà ní ìgbà ẹ̀ẹ̀kéjì Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà sì ṣe abẹ akọ òkúta, ó sì kọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilà, ní Gíbíátì-Hárálótù Wàyí o, ìdí tí Jóṣúà fi kọ wọ́n nílà nìyìí Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó ti Éjíbítì jáde wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun kú ní asálẹ̀ ní ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, gbogbo àwọn ọkùnrin tó jáde láti Éjíbítì ni a ti kọ ní ilà, síbẹ̀ gbogbo ènìyàn tí a bí nínú asálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní Éjíbítì ni wọn kò kọ ní ilà Àwọn ará Ísírẹ́lì rìn ní ihà fún ogójì ọdún títí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó tó ogun n jà nígbà tí wọ́n kúrò ni Éjíbítì fi kú, nítorí wọn kò gbọ́ràn sí Olúwa Nítorí Olúwa ti búra fún wọn pé wọn kò ní rí ilẹ̀ tí òun ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn láti fí fun wa, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin Bẹ́ẹ̀ ni ó gbé àwọn ọmọ wọn dìde dípò wọn, àwọn wọ̀nyí sì ni Jóṣúà kọ ní ilà Wọ́n wà ní aláìkọlà nítorí a kò tíì kọ wọ́n ní ilà ní ojú ọ̀nà Lẹ́yìn ìgbà tí gbogbo orílẹ̀ èdè náà kọ ilà tan, wọ́n dúró ní ibi tí wọ́n wà ní ibùdó títí ilà wọn fi jinná Nígbà náà ní Olúwa wí fún Jóṣúà pé, Ní òní ni mo yí ẹ̀gàn Éjíbítì kúrò ní orí yín Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Gílígálì títí ó fi di òní yìí Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹ́rìnlá oṣù náà nígbà tí wọ́n pàgọ́ ní Gílígálì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ọdún Àjọ-ìrékọjá Ní ọjọ́ kéjì Àjọ-ìrékọjá, ní ọjọ́ náà gan-an ni, wọ́n jẹ nínú àwọn irè oko ilẹ̀ náà àkàrà aláìwú, àti ọkà yíyan Mánà náà sì tan ní ọjọ́ kéjì tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ilẹ̀ náà mú jáde kò sì sí mánà kankan mọ́ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n ní ọdún náà wọ́n jẹ irè oko ilẹ̀ Kénánì Nígbà tí Jóṣúà sún mọ́ Jẹ́ríkò, ó wo òkè ó sì rí ọkùnrin kan tí ó dúró ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú idà ní ọwọ́ rẹ̀ Jóṣúà sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, Ǹjẹ́ ìwọ wà fún wa tàbí fún ọ̀ta a wa Kì í ṣe fún èyíkéyìí ó fèsì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí ogun Olúwa ni mo wá nísinsin yìí Nígbà náà ni Jóṣúà sì wólẹ̀ ní iwájú u rẹ̀ ní ìbẹ̀rù, ó sì bi í léèrè, Kí ni Olúwa ní í sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Olórí ogun Olúwa sì dá a lóhùn pé, Bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹṣẹ̀ rẹ, nítorí pé ibi tí ìwọ dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni Jóṣúà sì ṣe bẹ́ẹ̀ Wàyí oí a ti há Jẹ́ríkò mọ́lé nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ẹnikẹ́ni kò jáde, ẹnikẹ́ni kò sì wọlé Nígbà náà ni Olúwa wí fún Jóṣúà pé, Wò ó, mo ti fi Jẹ́ríkò lé ọ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọba rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀ Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan pẹ̀lú gbogbo àwọn jagunjagun Ẹ ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà Jẹ́ kí àwọn àlùfáà méje gbé fèrè ìwo àgbò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Ní ọjọ́ kéje Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, pẹ̀lú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè Nígbà tí ẹ bá gbọ́ ohùn un fèrè náà, kí àwọn ènìyàn hó-yèè ní igbe ńlá, nígbà náà ni odi ìlú náà yóò sì wó lulẹ̀, àwọn ènìyàn yóò sì lọ sí òkè, olúkúlùkù yóò sì wọ inú rẹ̀ lọ tààrà Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà ọmọ Núnì pe àwọn àlùfáà ó sì wí fún wọn pé, Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa náà kí àwọn àlùfáà méje tí ó ru fèrè ìwo wà ní iwájú u rẹ̀ Ó sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé, Ẹ lọ, kí ẹ sì yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn olùsọ́ tí ó hámọ́ra kọjá ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Nígbà tí Jóṣúà ti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ tán, àwọn àlùfáà méje tí wọ́n gbé fèrè méje ní iwájú Olúwa kọjá sí iwájú, wọ́n sì fọn fèrè wọn, àpótí ẹ̀rí Olúwa sì tẹ̀-lé wọn Àwọn olùṣọ tí ó hámọ́ra sì lọ níwájú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè, olùṣọ́ ẹ̀yìn sì tẹ̀-lé àpótí ẹ̀rí náà Ní gbogbo àsìkò yìí fèrè sì ń dún Ṣùgbọ́n Jóṣúà tí pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, Ẹ kò gbọdọ̀ kí-gbe ogun, ẹ kò gbọdọ̀ gbé ohùn yín sókè, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ kan títí ọjọ́ tí èmi yóò sọ fún un yín pé kí ẹ hó Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sì hó! Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí àpótí ẹ̀rí Olúwa yí ìlú náà ká, ó sì yí i ká lẹ́ẹ̀kan Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà padà sí ibùdó wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún alẹ́ náà Jóṣúà sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa Àwọn àlùfáà méje tí ó gbé ìpè ìwo àgbò méje ń lọ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa , wọ́n sì ń fọ́n àwọn ìpè àwọn tí ó há mọ́ra ogun ń lọ níwájú u wọn àwọn ọmọ tó wà lẹ́yìn sì ń tọ àpótí ẹ̀rí Olúwa lẹ́yìn, àwọn àlùfáà sì ń fọn ìpè bí wọ́n ti ń lọ Ní ọjọ́ kéjì, wọ́n yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan wọ́n sì padà sí ibùdó Wọ́n sì ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà Ní ọjọ́ kéje, wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní àfẹ̀mọ́júmọ́, wọ́n sì wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí i ti ìṣáájú, ní ọjọ́ kéje nìkanṣoṣo ni wọ́n wọ́de ogun yí ìlú náà ká nígbà méje Ní ìgbà kéje, nígbà tí àwọn àlùfáà fọn fèrè, Jóṣúà pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, Ẹ hó! Nítorí pé Olúwa ti fún un yín ní ìlú náà Ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀ ni yóò jẹ́ ìyàṣọ́tọ̀ fún Olúwa Ráhábù tí ó jẹ́ panṣágà nìkan àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ ni a ó dásí nítorí tí ó pa àwọn ayọ́lèẹ̀wò tí á rán mọ́ Ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ̀yin kí ó má ba à ṣojú kòkòrò nípa mímú nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ ó sọ ibùdó Ísírẹ́lì di ìparun Kí ẹ sì mú wàhálà wá sórí i rẹ̀ Gbogbo fàdákà àti wúrà àti ohun èlò idẹ àti irin jẹ́ mímọ́ fún Olúwa , wọ́n yóò wá sínú ìsúra Olúwa Nígbà tí àwọn àlùfáà fọn ìpè, àwọn ènìyàn náà sì hó Ó sì ṣe, bí àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìró ìpè, tí àwọn ènìyàn sì hó ìhó-ńlá, odi ìlú náà wó lulẹ̀ bẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ya wọ inú ìlú náà lọ tààrà, wọ́n sì kó ìlú náà Wọ́n ya ìlú náà sọ́tọ̀ fún Olúwa àti fún ìparun, wọ́n sì fi idà run gbogbo ohun alààyè ní ìlú náà—ọkùnrin àti obìnrin, ọ́mọdé, àti àgbà, màlúù, àgùntàn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Jóṣúà sì sọ fún àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ti wá ṣe ayọlẹ̀ náà wò pé, Ẹ lọ sí ilé aṣẹ́wó nì, kí ẹ sì mu jáde àti gbogbo ohun tí í ṣe tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ tí búra fún un Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó lọ ṣe ayọ́lẹ̀wò wọlé lọ, wọ́n sì mú Ráhábù jáde, baba rẹ̀, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní Wọ́n sì mú gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde, wọ́n sì fi wọ́n sí ibìkan ní ìta ibùdó àwọn ará Ísírẹ́lì Nígbà náà ni wọ́n ṣun gbogbo ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú u rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fi fàdákà, wúrà ohun èlò-idẹ àti irin sínú ìsúra ilé Olúwa Ṣùgbọ́n Jóṣúà dá Ráhábù asẹ́wó pẹ̀lú gbogbo ìdílé e rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tirẹ̀ sí nítorí pé, ó pa àwọn ọkùnrin tí Jóṣúà rán gẹ́gẹ́ bí ayọ́lẹ̀wò sí Jẹ́ríkò mọ́ Ó sì ń gbé láàrin ará Ísírẹ́lì títí di òní yìí Ní àkókò náà Jóṣúà sì búra pé Ègún ni fún ẹni náà níwájú Olúwa tí yóò dìde, tí yóò sì tún ìlú Jẹ́ríkò kọ́ Pẹ̀lú ikú àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni yóò fi pilẹ̀ rẹ̀ ikú àbíkẹ́yìn in rẹ̀ ní yóò fi gbé ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ ró Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wà pẹ̀lú Jóṣúà òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà Ìsẹ́gun Lórí Áì Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàṣọ́tọ̀, Ákánì ọmọ Kámì, ọmọ Símírì, ọmọ Ṣérà, ẹ̀yà Júdà, mú nínú wọn Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ará Ísírẹ́lì Jóṣúà rán àwọn ọkùnrin láti Jẹ́ríkò lọ sí Áì, tí ó sún mọ́ Bẹti-Áfẹ́nì ní ìlà-oòrùn Bétélì, ó sì sọ fún wọn pé, Ẹ gòkè lọ kí ẹ sì ṣe amí Bẹ́ẹ̀ ni àwọn arákùnrin náà lọ, wọ́n sì yọ́ Áì wò Nígbà tí wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ Jósúà, wọ́n wí pé, Kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn ni ó ni láti gòkè lọ bá Áì jà Rán ẹgbẹ̀rún méjì tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin láti gbà á, kí ó má ṣe dá gbogbo àwọn ènìyàn ní agara, nítorí ìba ọkùnrin díẹ̀ ní ó wà níbẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ní àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin lọ ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Áì lé wọn sá, wọ́n sì pa àwọn bí mẹ́rìndínlógójì nínú wọn Wọ́n sì ń lépa àwọn ará Ísírẹ́lì láti ibodè ìlú títí dé Ṣébárímù, wọ́n sì pa àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ Àyà àwọn ènìyàn náà sì já, ọkàn wọn sì pámi Jósúà sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dojú bolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa títí di àṣálẹ́ Àwọn àgbà Ísírẹ́lì sì ṣe bákan náà, wọ́n ku eruku sí orí i wọn Jósúà sì wí pé, Háà, Olúwa Ọlọ́run alágbára, nítorí i kiín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá a Jọ́dánì, láti fi wọ́n lé àwọn ará Ámórì lọ́wọ́ láti pa wọn run Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdì kéjì Jọ́dánì Olúwa , kín ni èmi yóò sọ nísinsin yìí tí Ísírẹ́lì sì ti sá níwájú ọ̀ta a rẹ̀ Àwọn Kénánì àti àwọn ènìyàn ìlú tí ó kù náà yóò gbọ́ èyí, wọn yóò sì yí wa ká, wọn yóò sì ké orúkọ wa kúrò ní ayé Kí ni ìwọ ó ha ṣe fún orúkọ ńlá à rẹ Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé, Dìde! Kín ni ìwọ ń ṣe tí ó fi dojú bolẹ̀ Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀ Wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́ Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, Wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn Ìdí nì-yí tí àwọn ará Ísírẹ́lì kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀ta wọn wọ́n yí ẹ̀yín wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀ta a wọn nítorí pé àwọn gan-an ti di ẹni ìparun Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò se pé ẹ̀yin pa ohun ìyàṣọ́tọ̀ run kúrò ní àárin yín Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́ Sọ fún wọn pé, Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí Ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárin yín, Ìwọ Ísírẹ́lì Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀ta a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò  Ní òwúrọ̀ kí ẹ mú ará yín wá ṣíwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan Ẹ̀yà tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, agbo ilé tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìdílé tí Olúwa bá sì mú yóò wá sí iwájú ní ẹni kọ̀ọ̀kan Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàṣọ́tọ̀ náà, a ó fi iná paárun, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní Ó ti ba májẹ̀mú Olúwa jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Ísírẹ́lì!  Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kéjì, Jóṣúà mú Ísírẹ́lì wá ṣíwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, a sì mú ẹ̀yà Júdà Àwọn agbo ilé e Júdà wá sí iwájú, ó sì mú agbo ilé Sérátì Ó sì mú agbo ilé Sérátì wá ṣíwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, a sì mú ìdílé Símírì Jóṣúà sì mú ìdílé Símírì wá ṣíwájú ní ọkùnrin kọ̀ọ̀kan, a sì mú Ákánì ọmọ Kámì, ọmọ Símírì, ọmọ Sérà ti ẹ̀yà Júdà Nígbà náà ní Jóṣúà sọ fún Ákánì pé, Ọmọ mi fi ògo fún Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí o sì fi ìyin fún un Sọ fún mi ohun tí ìwọ ti ṣe, má ṣe fi pamọ́ fún mi Ákánì sì dáhùn pé, Òtítọ́ ni mo ti ṣẹ̀ sí Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì Nǹkan tí mo ṣe nì yí Nígbà tí mo rí ẹ̀wù Bábílónì kan tí ó dára nínú ìkógún, àti igba sẹ́kélì fàdákà àti díndi wúrà olóṣùnwọ̀n àádọ́ta ṣẹ́kélì, mo ṣe ojú kòkòrò wọn mo sì mú wọn Mo fi wọ́n pamọ́ ní abẹ́ àgọ́ ọ̀ mi àti fàdákà ní abẹ́ ẹ rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà ran àwọn òjíṣẹ́, wọ́n sì ṣáré wọ inú àgọ́ náà, ó sì wà níbẹ̀, a sì fi pamọ́ nínú àgọ́ ọ rẹ̀, àti fàdákà ní abẹ́ ẹ rẹ̀ Wọ́n sì mú àwọn nǹkan náà jáde láti inú àgọ́ rẹ̀, wọ́n mú wọn wá fún Jóṣúà àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì fi wọ́n lélẹ̀ níwájú Olúwa Nígbà náà ni Jóṣúà pẹ̀lú gbogbo Ísírẹ́lì, mú Ákánì ọmọ Sérà, fàdákà, ẹ̀wù àti wúrà tí a dà, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àgùntàn àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ni, wọ́n sì kó wọn lọ sí ibi àfonífojì Ákórì Jóṣúà sì wí pé, Èé ṣe tí ìwọ mú wàhálà yìí wá sí orí i wa Olúwa yóò mú ìpọ́njú wá sí orí ìwọ náà lónìí Nígbà náà ni gbogbo Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sọ àwọn tó kù ní òkúta pa tán, wọ́n sì jó wọn níná Wọ́n sì kó òkítì òkúta ńlá lé Ákánì lórí títí di òní yìí Nígbà náà ní Olúwa sì yí ìbínú gbígbóná rẹ̀ padà Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Àfonífojì Ákórì láti ìgbà náà Ìparun Áì Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Jóṣúà pé, Má ṣe bẹ̀rù, kí àyà kí ó má ṣe fò ọ́ Kó gbogbo àwọn ọmọ ogun pẹ̀lúù rẹ, kí ẹ gòkè lọ gbógun ti Áì Nítorí mo ti fi ọba Áì, àwọn ènìyàn an rẹ̀, ìlú u rẹ̀ àti ilẹ̀ ẹ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́ Ìwọ yóò sì ṣe sí Áì àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Jẹ́ríkò àti ọba rẹ̀, ohun ìkógun wọn àti ohun ọ̀sìn wọn ni kí ẹ̀yin mú fún ara yín Rán ènìyàn kí wọ́n ba sí ẹ̀yìn ìlú náà Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun jáde lọ láti dojú kọ Áì Ó sì yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún àwọn ọkùnrin ogun rẹ̀ ti ó yakin, ó sì rán wọn lọ ní òru Pẹ̀lú àwọn àṣẹ wọ̀nyí Ẹ fi etí sílẹ̀ dáadáa Ẹ ba sí ẹ̀yìn ìlú náà Ẹ má ṣe jìnnà sí i púpọ̀ Kí gbogbo yín wà ní ìmúra-sílẹ̀ Èmi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lúù mi yóò súnmọ́ ìlú náà Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà bá jáde sí wa, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìṣáájú, àwa yóò sì ṣá kúrò níwájú u wọn Wọn yóò sì lépa wa títí àwa ó fi tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà, nítorí tí wọn yóò wí pé, wọ́n ń sá lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ṣe ní ìṣáájú Nítorí náà bí a bá sá kúrò fún wọn, ẹ̀yin yóò dìde kúrò ní ibùba, ẹ ó sì gba ìlú náà Olúwa Ọlọ́run yín yóò sì fi lé e yín lọ́wọ́ Nígbà tí ẹ bá ti gba ìlú náà, kí ẹ sì ti iná bọ̀ ọ́ Kí ẹ ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ Mo ti fi àṣẹ fún un yín ná Nígbà náà ni Jóṣúà rán wọn lọ Wọ́n sì lọ sí ibùba, wọ́n sì sùn ní àárin Bétélì àti Áì, ní ìwọ̀-oòrùn Áì Ṣùgbọ́n Jóṣúà wá dúró pẹ̀lú àwọn ènìyan ní orú ọjọ náà Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kéjì Jóṣúà kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, òun àti àwọn olórí Ísírẹ́lì, wọ́n wọ́de ogun lọ sí Áì Gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì súnmọ́ tòsí ìlú náà, wọ́n sì dé iwájú u rẹ̀ Wọ́n sì pàgọ́ ní ìhà àríwá Áì Àfonífojì sì wà ní agbede-méjì wọn àti ìlú náà Jóṣúà sì ti fi bí ẹgbẹ̀rún márùn ún ọmọ ogun pamọ́ sí àárin Bétélì àti Áì, sí ìwọ̀-òòrùn ìlú náà Wọ́n sì yan àwọn ọmọ ogun sí ipò wọn, gbogbo àwọn tí ó wà ní ibùdó lọ sí àríwá ìlú náà àti àwọn tí ó ṣápamọ́ sí ìwọ̀-òrùn rẹ̀ Ní òru ọjọ́ náà Jóṣúà lọ sí àfonífojì Nígbà tí ọba Áì rí èyí, òun àti gbogbo ọkùnrin ìlú náà yára jáde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù láti pàdé ogun Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aginjù Ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé àwọn kan wà ní ibùba ní ẹ̀yìn ìlú náà Jóṣúà àti gbogbo àwọn Ísírẹ́lì sì ṣe bí ẹni tí a lé padà níwájú wọn, wọ́n sì ṣá gba ọ̀nà ihà A sì pe gbogbo àwọn ọkùnrin Áì jọ láti lépa wọn, wọ́n sì lépa Jóṣúa títí wọ́n fi tàn wọ́n jáde nínú ìlú náà Kò sì ku ọkùnrin kan ní Áì tàbi Bétélì tí kò tẹ̀lé Ísírẹ́lì Wọ́n sì fi ìlẹ̀kùn ibodè náà sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n sì ń lépa àwọn ará Ísírẹ́lì Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Jóṣuà pé, Na ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọ rẹ sí Áì, nítorí tí èmi yóò fi ìlú náà lé ọ ní ọwọ́ Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà sì na ọ̀kọ̀ ọwọ́ ọ rẹ̀ sí Áì Bí ó ti ṣe èyí tán, àwọn ọkùnrin tí ó ba sì dìde kánkán kúrò ní ipò wọn, wọ́n sáré ṣíwájú Wọn wọ ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára ti iná bọ̀ ọ́ Àwọn ọkùnrin Áì bojú wo ẹ̀yìn, wọ́n rí èéfín ìlú náà ń gòkè lọ sí ọ̀run, ṣùgbọ́n wọn kò rí, àyè láti sá àsálà lọ sí ibìkan kan, nítorí tí àwọn ará Ísírẹ́lì tí wọ́n tí ń sálọ sí ihà ti yípadà sí àwọn tí ń lépa wọn Nígbà tí Jóṣúà àti gbogbo àwọn ará Ísírẹ́lì rí i pé àwọn tí ó ba ti gba ìlú náà, tí èéfín ìlú náà sì ń gòkè, wọ́n yí padà wọ́n sì kọlu àwọn ọkùnrin Áì Àwọn ọmọ ogun tí ó ba náà sì yípadà sí wọn láti inú ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wà ní agbede-méjì àwọn ará Ísírẹ́lì ní ìhà méjèèjì Ísírẹ́lì sì pa wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì jẹ́ kí ọ̀kan kí ó yè tàbí kí ó ṣálọ nínú un wọn Ṣùgbọ́n wọ́n mú ọba Áì láàyè, wọ́n sì mu-un tọ Jósúà wá Nígbà tí Ísírẹ́lì parí pípa àwọn ọkùnrin Áì ní pápá àti ní ihà ní ibi tí wọ́n ti lépa wọn lọ, nígbà tí wọ́n pa gbogbo wọn tan, gbogbo àwọn Ísírẹ̀lì sì padà sí Áì, wọ́n sì pa àwọn tí ó ṣẹ́kù síbẹ̀ Ẹgbẹ̀rún méjìlá ọkùnrin àti obìnrin ni ó kú ní ọjọ́ náà-gbogbo wọn jẹ́ àwọn ènìyàn Áì Nítorí tí Jósúà kò fa ọwọ́ ọ rẹ̀ tí ó di ọ̀kọ̀ mú sí ẹ̀yìn, títí ó fi pa gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú Áì run Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì kó ẹran ọ̀sìn àti ìkógún ti ìlú yìí fún ara wọn, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Jóṣúà Jóṣúà sì jó Áì, ó sì sọ ọ́ di ààtàn, àní ahoro di òní yìí Ó sì gbé ọba Áì kọ́ orí igi, ó sì fi kalẹ̀ síbẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ Bí òòrùn sì ti wọ̀ ni Jóṣúà pàṣẹ fún wọn láti sọ òkú rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní orí igi, kí wọn sì wọ́ ọ jù sí àtiwọ ẹnu ibodè ìlú náà Wọ́n sì kó òkítì òkúta ńlá lé e ní orí, èyí tí ó wà títí di òní yìí Nígbà náà ni Jóṣúà mọ pẹpẹ kan fún Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní òkè Ébálì, gẹ́gẹ́ bí Móṣè ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ó sì kọ́ ọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú Iwé Òfin Móṣè, pẹpẹ odindi òkúta, èyí tí ẹnìkan kò fi ohun èlò irin kàn rí Wọ́n sì rú ọrẹ ẹbo ṣísun àti ọrẹ àlàáfíà ní orí i rẹ̀ sí Olúwa Níbẹ̀ ní ojú àwọn ará Ísírẹ́lì, Jósúà sì ṣe àdàkọ òfin Mósè èyí tí ó ti kọ sí ara òkúta náà Gbogbo Ísírẹ́lì, àlejò àti ọmọ ìlú, pẹ̀lú àwọn àgbà, olórí àti onídàájọ́ dúró ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àpótí ẹ̀rí Olúwa tí ó kọjú sí àwọn àlùfáà tí ó rù ú, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì Ìdajì àwọn ènìyàn náà dúró ní Òkè Gérísímù, àwọn ìdajì si dúró ni òkè Ébálì, gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ rí, pé kí wọn súre fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì Lẹ́yìn èyí, Jóṣúà sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin ìbùkún àti ègún-gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Òfin Kò sí ọ̀rọ̀ kan nínú gbogbo èyí tí Mósè pàṣẹ, tí Jósúà kò kà ní iwájú gbogbo àjọ Ísírẹ́lì, títí fi kan àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn, àti àwọn àlejò tí ń gbé ní àárin wọn Ìwa Àrékérekè Gíbíónì Nísinsinyìí, nígbà tí gbogbo ọba tó wà ní ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, àwọn náà tí ó wà ní orí òkè àti àwọn tí ó wà ní ẹṣẹ̀ òkè, àti gbogbo àwọn tí ó wà ní agbégbé Òkun ńlá títí ó fi dé Lẹ́bánónì wọ́n sì kó ara wọn jọ láti bá Jósúà àti Ísírẹ́lì jagun Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ènìyàn Gíbíónì gbọ́ ohun tí Jóṣúà ṣe sí Jẹ́ríkò àti Áì, wọ́n dá ọgbọ́n ẹ̀tàn Wọ́n lọ bí aṣojú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn tí kún fún àwọn àpò tó ti gbó, àti àwọn awọ ọtí wáìnì tó ti gbó tí a tún rán Àwọn ọkùnrin náà sì wọ bàtà àti aṣọ tí ó ti gbó Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n pèsè fún ara wọn sì bu Wọ́n sì tọ Jóṣúà lọ ní ibùdó ní Gílígálì, wọ́n sì sọ fún òun àti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé, Ìlú òkèrè ní àwọn ti wá, ẹ ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wa Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ fún àwọn ará Hífì pé, Ṣùgbọ́n bóyá tòsí wa ni ẹ ń gbé Báwo ni a ó ṣe lè se àdéhùn pẹ̀lú yín Ìránṣẹ́ rẹ ní àwa í ṣe Wọ́n sọ fún Jóṣúà Ṣùgbọ́n Jóṣúà béèrè, Ta ni yín àti pé níbo ni ẹ̀yín ti wá Wọ́n sì dáhùn pé Ní ilẹ̀ òkèèrè ní àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wá, nítorí orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ Nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Éjíbítì, àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe sí ọba àwọn Ámórì méjèèje tí ń bẹ ní òkè Jọ́dánì, sí Síhónì ọba Héṣíbónì, àti Ógù ọba Básánì, tí wọ́n jọba ní Áṣítarótù Àwọn àgbà wa àti gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú wa sọ fún wa pé, Ẹ mú oúnjẹ lọ́wọ́ fún ìrìnàjò yín, ẹ lọ pàdé wọn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé, Àwa ni ìránṣẹ́ yín, ẹ dá àdéhùn pẹ̀lú wa   Gbígbóná ní a mú oúnjẹ ní ojí nílé ní oji tí à ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín Ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí ó ṣe gbẹ àti bí ó sì ṣe bu nísinsinyí Àti ìgò wáìnì wọ̀nyí, tí àwa rọ kún tuntun ni, ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí wọ́n ti sán Asọ àti bàtà wa ni ó sì ti gbó nítorí ìrìnàjò ọ̀nà jínjìn Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì yẹ oúnjẹ wọn wò, wọn kò sì wádìí ní ọwọ́ Olúwa Nígbà náà ni Jósúà ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wọn láti dá wọn sí, àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn fi ọwọ́ sí àdéhùn náà nípa ṣíṣe ìbúra Ní ẹ̀yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn ará Gíbíónì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ pé aládùúgbò wọn ni wọ́n, tí ń gbé ní tòsí wọn Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde, wọ́n sì dé ìlú wọn ní ọjọ́ kẹ́ta Gíbíónì, Kéfírà, Béérótù àti Kiriati-jéárímù Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò si kọlù wọ́n, nítorí pé àwọn àgbààgbà ìjọ ènìyàn ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì Gbogbo ènìyàn sì kùn sí àwọn àgbààgbà náà, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn olórí dáhùn pé, Àwa ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, a kò sì lè fọwọ́ kàn wọ́n nísinsinyí Èyí ní àwa yóò ṣe sí wọn, Àwa yóò dá wọn sí, kí ìbínú kí ó má baà wá sorí wa, nítorí ìbúra tí a búra fún wọn Wọ́n tẹ̀ṣíwájú, Ẹ dá wọn sí, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn jẹ́ gégigégi àti apọnmi fún gbogbo ìlú Àwọn àgbààgbà náà sì mú ìlérí wọn sẹ fún wọn Nígbà náà ni Jósúà pe àwọn ọmọ Gíbíónì jọ pé, Èé ṣe tí ẹ̀yin fí tàn wá wí pe, Àwa gbé ní ibi tí ó jìnnà sí yín, nígbà tí ó jẹ́ pé tòsí wa ní ẹ̀yin ń gbé Nísinsinyí, ẹ̀yin di ẹni ègún Ẹ̀yin kò sì ní kúrò ní gégigégi àti apọnmi fún ilé Ọlọ́run mi Wọ́n sì dá Jóṣúà lóhùn pé, Nítorí tí a sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ dájú ṣáká bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, láti fún yín ní gbogbo ilẹ̀ náà, kí ó sì pa gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà run kúrò ní iwájú yín Nítorí náà, àwa bẹ̀rù ẹ̀mí wa nítorí yín, èyí sì ni ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀ Nísinsinyí, àwa wà ní ọwọ́ yín Ohunkóhun tí ẹ bá rò pé ó yẹ ó si tọ́ lójú yín ní kí ẹ fi wá ṣe Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà sì gbà wọ́n là kúrò ní ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Wọn kò sì pa wọ́n Ní ọjọ́ náà ni ó sọ àwọn Gíbíónì di aṣẹ́gi àti apọnmi fún àwọn ará ìlú àti fún pẹpẹ Olúwa ní ibi tí Olúwa yóò yàn Báyìí ní wọ́n wà títí di òní yìí Ẹ̀sẹ̀ Àti Ìparun Àwọn Aláìwà-Bí-Ọlọ́run JÚDÀ, ìránṣẹ́ Jésù Kírísítì àti arákùnrin Jákọ́bù, Sí àwọn tí a pè, olùfẹ́ nínú Ọlọ́run Baba, tí a pamọ́ fún Jésù Kírísítì Kí àánú, àlàáfíà àti ìfẹ́ kí ó máa jẹ́ tiyín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmí ní ìtara láti kọ̀wé sí i yín nípa ìgbàlà tí í ṣe ti gbogbo ènìyàn, n kò gbọdọ̀ má kọ̀wé sí yín, kí ń sì gbà yín ní ìyànjú láti máa jà fitafita fún ìgbàgbọ́, tí a ti fi lé àwọn ènìyàn mímọ́ lọ́wọ́ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo Nítorí àwọn ènìyàn kan ń bẹ tí wọn ń yọ́ wọlé, àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ń yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí wọ̀bìà, tí wọn sì ń ṣẹ́ Olúwa wa kansoso náà, àní Jésù Kírísítì Olúwa Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́ Àti àwọn ańgẹ́lì tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìṣàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ ọjọ́ ńlá nì Àní bí Sódómù àti Gomorà, àti àwọn ìlú agbégbé wọn, ti fi ara wọn fún àgbérè ṣíṣe, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ará àjèjì lẹ́yìn, àwọn ni ó fi lélẹ̀ bí àpẹrẹ, àwọn tí ó ń jìyà iná àìnípẹ̀kun Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjoye, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búbúrú sí àwọn ọlọ́lá Ṣùgbọ́n Mákẹ́lì, olórí awọn ańgẹ́lì, nígbà tí ó ń bá Èṣù jiyàn nítórí òkú Mósè, kò sọ ọ̀rọ̀ òdì sí i Ṣùgbọ́n ó wí pé, Olúwa bá ọ wí Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí n sọ̀rọ̀ òdì sí ohun gbogbo ti kò yé wọn ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí wọn mọ̀ nípa ìròfún-ara, bí ẹranko tí kò ní ìyè, nípaṣẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n di ẹni ìparun Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Káínì, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìsìnà Bálámù nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kórà Àwọn wọ̀nyí ní ó jẹ́ àbàwọ́n nínú àṣè ìfẹ́ yín, nígbà tí wọ́n ń bá yín jẹ àsè, àwọn olùsọ́ àgùntàn ti ń bọ́ ara wọn láìbẹ̀rù Wọ́n jẹ́ ìkùùkuu láìrọ òjò, tí a ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ gbá kiri àwọn igi aláìléso ní àkókò èso, wọ́n kú lẹ́ẹ̀méjì, a sì fà wọn tú ti-gbòǹgbò-ti-gbòǹgbò Wọ́n jẹ́ ìjì líle ti ń ru ní ojú omi òkun, ti ń hó ìfófó ìtìjú wọn jáde alárìnkiri ìràwọ̀, àwọn tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè láéláé Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni Énọ́kù, ẹni keje láti ọ̀dọ̀ Ádámù, sọ̀tẹ́lẹ̀ nípa wọn pé Kíyèsí i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ mímọ́, láti ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn, láti dá gbogbo àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run lẹ́bi ní ti gbogbo iṣẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run wọn, ti wọ́n ti fi àìwà-bí-Ọlọ́run ṣe, àti ní ti gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́sẹ̀ aláìwà-bí-Ọlọ́run ti sọ sí i Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní àwọn ti ń kùn, àwọn aláròyé, ti ń rìn nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn wọn ń gbéraga nipa ara wọn, wọ́n sì ń ṣáta àwọn ènìyàn mìíràn fún èrè ara wọn Ṣùgbọ́n ẹyin olùfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ tí a ti sọ ṣááju láti ọwọ́ àwọn Àpósítélì Olúwa wa Jésù Kírísítì Bí wọn ti wí fún yín pé, Nígbà ìkẹyìn àwọn ẹlẹ́gàn yóò wà, tí wọn yóò máa rìn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run ti ara wọn Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn ẹni tí ń ya ara wọn sí ọ̀tọ̀, àwọn ẹni tí ara, tí wọn kò ni Ẹ̀mí Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ti ẹ ń gbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín tí ó mọ́ jùlọ, ti ẹ ń gbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímọ́ Ẹ máa pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ̀yin ti ń rétí àánú Olúwa wa Jésù Kírísítì tí yóò mú yín dé ìyè àìnípẹ̀kun Ẹ máa yí àwọn tí ń ṣe iyèméjì lọ́kàn padà Ẹ máa gba àwọn ẹlòmíràn là, nípa fífà wọ́n yọ kúrò nínú iná kí ẹ sì máa ṣàánú pẹ̀lú ìbẹ̀rù kí ẹ sì kórìíra ẹ̀wù tí ara ti sọ di èèrí Ǹjẹ́ mo fi yín lé ẹni tí o lè pa yín mọ́ kúrò nínú ìkọsẹ̀, tí o sì lè mú yín wá ṣíwájú ògo rẹ̀ láilábùkù pẹ̀lú ayọ̀ ńlá lọ́wọ́— tí Ọlọ́run ọlọ́gbọn níkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa, ní ògo àti ọlá ńlá, ìjọba àti agbára, nísinsìn yìí àti títí láéláé! Àmín Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan, nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn! Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí ó wà nípò opó, Ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọba bìnrin láàrin ìlú ni ó padà di ẹrú Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sunkún kíkorò pẹ̀lú omijé tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀ wọ́n ti di alátakò rẹ̀ Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú, Júdà lọ sí àjò Ó tẹ̀dó láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi Àwọn tí ó ń tẹ̀le ká a mọ́ ibi tí kò ti le sá àṣálà Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Ṣíónì ń sọ̀fọ̀, nítorí kò sẹ́ni tí ó wá láti jọ́sìn Ẹnu bodè pátapáta ni ó dahoro, àwọn Olórí àlùfáà ibẹ̀ kérora, àwọn ọ̀dọ́bìnrin rẹ̀ sì ń kẹ́dùn, òun gan-an wà pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn Aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀, nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, Olúwa ti fún un ní ìjìyà tó tọ́ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú, ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé Àwọn ọmọ ọba kùnrin dàbí i ìgalà tí kò rí ewé tútù jẹ nínú àárẹ̀ wọ́n sáré níwájú ẹni tí ó ń lé wọn Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ ni Jérúsálẹ́mù rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀ tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́ Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, kò sì sí olùrànlọ́wọ́ fún un Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ó wọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà Jérúsálẹ́mù sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ ó sì ti di aláìmọ́ Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀ ó kérora fúnra rẹ̀, ó sì lọ kúrò Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀, Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu olùtùnú kò sì sí fún un Wo ìpọ́njú mi, Olúwa , nítorí àwọn ọ̀ta ti borí Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé gbogbo ìní rẹ o rí àwọn ìlú abọ̀rìṣà tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ— àwọn tí o ti kọ̀ sílẹ̀ láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ wọ́n fi ohun ìní wọn se pàsípààrọ̀ oúńjẹ láti mú wọn wà láàyè Wò ó, Olúwa , kí o sì rò ó, nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀ Kò ha jẹ́ nǹkankan sí i yín Gbogbo ẹ̀yin tí ń ré kọjá, Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà tí a fi fún mi, ti Olúwa mú wá fún mi ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀ Ó rán iná láti òkè sọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi, ó sì yí mi padà Ó ti pa mí lára mó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti di síṣopọ̀ sí àjàgà ọwọ́ ọ rẹ̀ ni a fi hun ún papọ̀ Wọ́n ti yí ọrùn mi ká Olúwa sì ti dín agbára mi kù Ó sì ti fi mí lé àwọn tí n kò le dojúkọ lọ́wọ́ Olúwa kọ àwọn akọni mi sílẹ̀, ó rán àwọn ológun lòdì sí mi kí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ Olúwa tẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Júdà Ìdí nìyí tí mo fi ń sunkún tí omijé sì ń dà lójú mi, Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sími, kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà Àwọn ọmọ mi di aláìní nítorí ọ̀ta ti borí Ṣíónì na ọwọ́ jáde, ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un Olúwa ti pàṣẹ fún Jákọ́bù pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀ta fún un Jérúsálẹ́mù ti di ohun aláìmọ́ láàrin wọn Olóòtítọ́ ni Olúwa , ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀ Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn ẹ wò mí wò ìyà mi Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ni a ti kó lọ sí ìgbèékùn Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣùgbọ́n wọ́n tàn mí Àwọn olórí àlùfáà àti àgbààgbà mi ṣègbé sínú ìlú nígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹ tí yóò mú wọn wà láàyè Olúwa , wòó, bí mo ti wà nínú ìnira! Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi, ìdààmú dé bá ọkàn mi nítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi Ní gbangba ni idà ń parun ikú wà nínú ilé pẹ̀lú Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi, ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde, kí wọ́n le dàbí tèmi Jẹ́ kí ìwà ìkà wọn wá síwájú rẹ jẹ wọ́n níyà bí o se jẹ mí níyà nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi Ìrora mi pọ̀ ọkàn mi sì káàárẹ̀ Báwo ni Olúwa ṣe bo ọmọbìnrin Síónì pẹ̀lú ìkúùkù ìbínú rẹ̀! Ó sọ ògo Ísírẹ́lì kalẹ̀ Láti ọ̀run sí ayé kò rántí àpótí-ìtìṣẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀ Làìní àánú ni Olúwa gbé ibùgbé Jákọ́bù mì nínú ìrunú rẹ̀ ni ó wó ibi gíga ọmọbìnrin Júdà lulẹ̀ Ó ti mú ìjọba àti àwọn ọmọ aládé ọkùnrin lọ sínú ilẹ̀ ní àìlọ́wọ̀ Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó ké gbogbo ìwo Ísírẹ́lì Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò nígbà tí àwọn ọ̀tá dé Ó run ní Jákọ́bù bí ọ̀wọ́ iná ní àgọ́ àwọn ọmọbìnrin Síónì Ó na ọfà rẹ̀ bí ọtá ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múra Bí ti ọ̀ta tí ó ti parun ó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná sórí àgọ́ ọmọbìnrin Síónì Olúwa dà bí ọ̀tá ó gbé Ísírẹ́lì mì Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mì ó pa ibi gíga rẹ̀ run Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin Júdà Ó mú ìparun bá ibimímọ́, ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run Olúwa ti mú Síónì gbàgbé ọjọ́ àṣè àti ọ̀ṣẹ̀ tí ó yàn nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run ọba àti olórí àlùfáà Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀ ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀ Ó sì fi lé ọ̀ta lọ́wọ́ àwọn odi ààfin rẹ̀ wọ́n sì kígbe ní ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìpèjẹ tí a yàn Olúwa pinnu láti fa ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Síónì ya Ó gbé wọn sórí òṣùnwọ̀n, kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn Ó mú kí ilé-ìsọ́ àti odi rẹ̀ sọ̀fọ̀ wọ́n ṣòfò papọ̀ Ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀ òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́ Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, kò sí òfin mọ́, àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́ Àwọn àgbààgbà ọmọbìnrin Síónì jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́ wọ́n da eruku sí orí wọn wọ́n sì wọ aṣọ àkísà Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jérúsálẹ́mù ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀ Ojú mi kọ̀ láti sunkún, mo ń jẹ ìrora nínú mi, mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀ nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run, nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú ní òpópó ìlú Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn, Níbo ni àkàrà àti wáìnì wà Wò ó bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe ní àwọn òpópónà ìlú, bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò láti ọwọ́ ìyá wọn Kí ni mo le sọ fún ọ Pẹ̀lú u kí ni mo lè fi ọ́ wé, Ìwọ ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé, kí n lè tù ọ́ nínú, Ìwọ wúndíá bìnrin Síónì Ọgbẹ́ rẹ jìn bí òkun Ta ni yóò wò ọ́ sàn Ìran àwọn wòlíì rẹ jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ jẹ́ èké àti ìsìnà Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn sí ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù Èyí ha ni ìlú tí à ń pè ní àṣepé ẹwà, ìdùnnú gbogbo ayé Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn gbòòrò sí ọ wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payín keke wọ́n wí pé, A ti gbé e mì tán Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí tí a sì wá láti rí Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́ Ó ti sí ọ nípò láì láàánú, ó fún ọ̀tá ní ìsẹ́gun lórí rẹ, ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga Ọkàn àwọn ènìyàn kígbe jáde sí Olúwa Odi ọmọbìnrin Síónì, jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ ṣàn bí odò ní ọ̀sán àti òru má ṣe fi ara rẹ fún ìtura, ojú rẹ fún ìsinmi Dìde, kígbe sókè ní àsálẹ́, bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀ tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi níwájú Olúwa Gbé ọwọ́ yín sókè sí i nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀ tí ó ń kú lọ nítorí ebi ní gbogbo oríta òpópó Wòó, Olúwa , kí o sì rò ó Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ tí wọn ń se ìtọ́jú fún Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì ní ibi mímọ́ Olúwa Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀ sínú eruku àwọn òpópó àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ti ṣègbé nípa idà Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ Ìwọ pa wọ́n láìní àánú Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àṣè, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi Ní ọjọ́ ìbínú Olúwa kòsí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn, ni ọ̀ta mi parun Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú Ó ti lémi jáde ó sì mú mi rìn nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀ Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ padà sí mi síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́ Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran ara mi gbó ó sì tún ṣẹ́ egungun mi Ó ti fi mí sí ìgbèkùn ó sì ti yí mi ká pẹ̀lú ìkorò àti làálàá Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́ Ó ti tì mí mọ́lé nítorí náà n kò le è sálọ ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀ Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, ó kọ àdúrà mi Ó fi búlọ́kù òkúta dí ọ̀nà mi ó sì mú ọ̀nà mi wọ́ Bí i béárì tí ó dùbúlẹ̀, bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́ Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ ó fi mi sílẹ̀ láì sí ìrànlọ́wọ́ Ó fa ọfà rẹ̀ yọ ó sì fi mí sohun ìtafàsí Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀ Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn ènìyàn mi wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́ Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi Ó ti fi òkúta kán ẹyín mi ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku Mo ti jìnnà sí àlàáfíà Mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe Nítorí náà mo wí pé, Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú Olúwa Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́ Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí àánú rẹ kì í kùnà Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀ títóbi ni òdodo rẹ̀ Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́ Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a Ó dára kí a ní ṣùúrù fún ìgbàlà Olúwa Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́jẹ́, nítorí Olúwa ti fi fún un Jẹ́ kí ó bò ojú rẹ̀ sínú eruku— ìrètí sì lè wà Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ Olúwa títí láé Lóòtọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí náà títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀ Nítorí kò mọ̀ọ́mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn Kí ó tẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ níwájú ẹni ńlá Láti yí ìdájọ́ ènìyàn po, Ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀ Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀ tí Olúwa kò bá fàṣẹ sí i Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu ẹni ńlá ni dídára àti búburú tí ń wá Kí ló dé tí ẹ̀dá alàyè ṣe ń kùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa kí a sì dán an wò, kí a sì tọ Olúwa lọ Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa ìwọ ń parun láì sí àánú Ìwọ ti fi ìkuukù bo ara rẹ pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn láàrin orílẹ̀ èdè gbogbo Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn gbòòrò sí wa Àwa ti jìyà àti ìparun, nínú ìbẹ̀rù àti ewu Omijé ń ṣàn ní ojú mi bí odò nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run Ojú mi kò dá fún omijé, láì sinmi, títí ìgbà tí Olúwa síjú wolẹ̀ láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí dẹ mí bí ẹyẹ Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò wọ́n sì ju òkúta lù mí Orí mi kún fún omi, mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa , láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi Má ṣe di etí rẹ sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́, o sì wí pé, Má se bẹ̀rù Olúwa , ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, o ra ẹ̀mí mi padà O ti rí i, Olúwa , búburú tí a ṣe sí mi Gbé ẹjọ́ mi ró! Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn, gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi— Ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ sí mi ní gbogbo ọjọ́ Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde, wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn, kí o sì fi wọ́n ré Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú, lábẹ́ ọ̀run Olúwa Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù, wúrà dídára di àìdán! Òkúta ibi mímọ́ wá túká sí oríta gbogbo òpópó Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Síónì tí ó ṣe iyebíye, tí wọ́n wọn iye wúrà ṣe wá dàbí ìkòkò amọ̀ lásán iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò! Àwọn ọ̀wàwà pèsè ọmú wọn fún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kàn bí ògòǹgò ní aṣálẹ̀ Nítorí òùngbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́ lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ Ṣùgbọ́n kòsí ẹni tí ó fi fún wọn Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradára di òtòsì ní òpópó Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀ ni wọ́n sùn ní orí òkítì eérú Ìjìyà àwọn ènìyàn mi tóbi ju ti Sódómù lọ, tí a sí nípò ní òjijì láì sí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́ Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò dídì, wọ́n sì funfun ju wàrà lọ lára, wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa, ìrísí wọn dàbí sáfírè Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí wọ́n dúdú ju èédú wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó Ara wọn hun mọ́ egungun ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sàn ju àwọn tí ìyàn pa tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfò fún àìní oúnjẹ láti inú pápá Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánú ni wọ́n ṣe ọmọ wọn tí ó di oúnjẹ fún wọn nígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀ ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde Ó da iná ní Síónì tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́, tàbí àwọn ènìyàn ayé, wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọ odi ìlú Jérúsálẹ́mù Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì àti àìṣedédé àwọn olórí àlùfáà, tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo sílẹ̀ láàrin rẹ̀ Nísinsìnyí wọ́n ń rìn kiri ní òpópó bí ọkùnrin tí ó fọ́jú Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́n tí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́! ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn Ẹlọ! Ẹlọ! Ẹ má se fọwọ́ kàn wá! Àwọn ènìyàn láàrin orílẹ̀ èdè wí pé, Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́ Olúwa ti tú wọn ká fún-ra-ra-rẹ̀ kò sí bojú tó wọn mọ́ Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́, àti àánú fún àwọn àgbà Síwájú sí i, ojú wa kùnà fún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wò fún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri, àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́ Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níye nítorí òpin wa ti dé Àwọn tí ń lé wa yára ju idì ojú ọ̀run lọ wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkè wọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní ihà Ẹni àmì òróró Olúwa , èémí ìyè wa, ni wọ́n fi tàkúté wọn mú Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni àwa yóò máa gbé láàrin orílẹ̀-èdè gbogbo Ẹ yọ̀ kí inú yín sì dùn, ẹ̀yin ọmọbìnrin Édómù, ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ Húsì Ṣùgbọ́n, a ó gbé aago náà kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú ìwọ yóò yó bí ọ̀mùtí, ìwọ yóò sì rìn ní ìhòòhò Ìwọ ọmọbìnrin Síónì, ìjìyà rẹ yóò dópin kò ní mú ìgbékùn rẹ pẹ́ mọ́ Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Édómù, yóò jẹ ẹ̀sẹ̀ rẹ níyà yóò sì fi àìṣedédé rẹ hàn kedere Rántí, Olúwa , ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò, ilé wa ti di ti àjèjì Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba, àwọn ìyá wa ti di opó A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu igi wa di títà fún wa Àwọn tí ó ń lé wa sún mọ́ wa àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Éjíbítì àti Ásíríà láti rí oúnjẹ tótó jẹ Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì sí mọ́, àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn Àwọn ẹrú ń jọba lórí wa, kò sì sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa nítorí idà tí ó wà ní ihà Ẹran ara wa gbóná bí ààrò, ebi sì yó wa bí àárẹ̀ Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lò pọ̀ ní Síónì, àti àwọn wúndíá wa ní ìlú Júdà Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di ṣíṣo sókè ní ọwọ́ wọn kò sí ìbọ̀wọ̀ fágbà mọ́ Àwọn ọdọ́mọkùnrin wa ru òkúta àwọn ọmọkùnrin sì ńṣsàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi Àwọn àgbààgbà ti lọ kúrò ní ẹnu bodè ìlú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa Adé ti sí kúrò ní orí wa Ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀ Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa, nítorí èyí, ojú wa sì ṣú Fún òkè Síónì tí ó ti di ahoro lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri Ìwọ, Olúwa , jọba títí láé ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn Kí ló dé tí o n gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́ Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa , kí àwa kí ó le padà mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbà a nì Àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n Ọrẹ Ẹbọ Sísun Olúwa sì pe Mósè, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú àgọ́ àjọ Ó wí pé Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kí o sì wí fún wọn pé Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa , kí ọrẹ ẹbọ yín jẹ́ ẹran ọ̀sìn láti inú agbo ẹran tàbí láti inú ọ̀wọ́ ẹran  Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ sísun láti inú agbo ẹran kí òun kí ó mú akọ màlúù tí kò lábùkù Ó sì gbọdọ̀ múu wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ kí ó bá à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú Olúwa kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹbọ sísun náà yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò o rẹ̀, yóò sì jẹ́ ètùtù fún un Kí ó pa ọ̀dọ́ akọ màlúù náà níwájù Olúwa , lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà tí í se ọmọ Árónì yóò gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà yí pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ ká Òun yóò bó àwọ ara akọ ọ̀dọ́ màlúù náà, òun yóò sì gé e sí wẹ́wẹ́ Àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà yóò fi iná sí orí pẹpẹ, wọn yóò sì to igi sórí pẹpẹ náà Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà yóò tò ègé ẹran náà, pẹ̀lú orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí ori igi tó ń jó lórí pẹpẹ Kí ó fi omi ṣàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa  Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn agutan tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù, kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Olúwa , kí àwọn ọmọ Árónì tí í se àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì tò ègé ẹran náà, orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ Kí ó fi omi san nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ Ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí Olúwa  Bí ọrẹ tí a fẹ́ fi fún Olúwa bá jẹ́ ti àwọn ẹyẹ, kí ó mú àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé Kí àlùfáà mu wá sí ibi pẹpẹ, kí ó yín in lọ́rùn, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, kí ó sì ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ Kí ó yọ àjẹsí ẹyẹ náà pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, kí ó gbe lọ ṣí apá ìlà oòrùn pẹpẹ níbi tí eérú wà Kí ó gbá apá rẹ̀ méjèèjì mú, kí ó fà á ya, ṣùgbọ́n kí ó má yaá tan pátapáta Lẹ́yìn náà ni àlùfáà yóò sun ún lórí igi tí ó ń jó lórí pẹpẹ, ọrẹ ẹbọ sísun ni ọrẹ tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí Olúwa Ikú Nádábù àti Ábíhù Nádábù àti Ábíhù tí í ṣe ọmọ Árónì sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àìmọ́ níwájú Olúwa , èyí tó lòdì sí àṣẹ Olúwa Torí èyí iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa , ó sì jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú Olúwa Mósè sì sọ fún Árónì pé, Ohun tí Olúwa ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí pé  Ní àárin àwọn tó súnmọ́ mi, Èmi yóò fí ara mi hàn ní mímọ́ ojú gbogbo ènìyàn Ní a ó ti bu ọlá fún mi  Árónì sì dákẹ́ Mósè pe Másáélì àti Élísáfánì ọmọ Yúsíélì tí í ṣe arákùnrin Árónì, ó sọ fún wọn pé Ẹ wá, kí ẹ sì gbé àwọn arákùnrin yín jáde kúrò níwájú ibi mímọ́ lọ sí ẹ̀yìn ibùdó Wọ́n sì wá gbé wọn, pẹ̀lú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn ní ọrùn wọn lọ sí ẹ̀yìn ibùdó bí Mósè ti sọ Mósè sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóòkù, Élíásárì àti Ítamárì pé, ẹ má ṣe sọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ sí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, Olúwa yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí Olúwa fi iná parun Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá kúrò níbẹ̀, ẹ ó kùú, nítorí pé òróró ìtasórí Olúwa wà lórí yín Wọ́n sì ṣe bí Mósè ti wí Olúwa sì sọ fún Árónì pé Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle mìíràn nígbàkigbà tí ẹ bá n lọ inú àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín láti ìrandíran Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrin mímọ́ àti àìmọ́, láàrin èérí àti àìléérí Ẹ gbọdọ̀ kọ́ àwọn ara Ísírẹ́lì ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún wọn láti ẹnu Mósè Mósè sì sọ fún Árónì, Élíásárì àti Ítamárì àwọn ọmọ rẹ̀ yóòkù pé Ẹ mú ẹbọ ohun jíjẹ tó sẹ́kù láti inú ẹbọ àfinásun sí Olúwa , kí ẹ jẹ ẹ́ láì ní ìwúkàrà nínú, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ nítorí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ Ẹ jẹ́ ẹ́ ní ibi mímọ́, nítorí pé òun ni ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nínú ẹbọ tí a finá sun sí Olúwa nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe pa á láṣẹ Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ le jẹ igẹ̀ ẹran tí a fì níwájú Olúwa àti itan tí wọ́n gbé ṣíwájú Olúwa , kí ẹ jẹ wọ́n ní ibi tí a kà sí mímọ́, èyí ni a ti fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín yín nínú ẹbọ àlàáfíà àwọn ara Ísírẹ́lì Itan tí wọ́n mú wá àti igẹ̀ ẹran tí ẹ fì ni ẹ gbọdọ̀ mú wá pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ tí a finá sun láti le fí wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì Èyí yóò sì jẹ́ ìpín tìrẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nígbà gbogbo bí Olúwa ṣe pa á láṣẹ Nígbà tí Mósè wádìí nípa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tó sì rí i pé wọ́n ti sun ún, ó bínú sí Élíásárì àti Ítamárì, àwọn ọmọ Árónì yóòkù, ó sì bèèrè pé, Èéṣe tí ẹ kò jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní agbégbé ibi mímọ́ Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, a fi fún yín láti lè mú ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ ènìyàn kúrò nípa fífi ṣe ètùtù fún wọn níwájú Olúwa Níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí ibi mímọ́, ẹ̀ bá ti jẹ ewúrẹ́ náà ní agbégbé ibi mímọ́ bí mo ṣe pa á láṣẹ Árónì sì dá Mósè lóhùn pé, Lónìí tí wọ́n rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun wọn níwájú Olúwa ni irú èyí tún sẹlẹ̀ sí mi Ǹjẹ́ inú Olúwa yóò wá dùn bí mo bá jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí Nígbà tí Mósè gbọ́ èyí, ọkàn rẹ̀ balẹ̀ Oúnjẹ Tó Mọ́ Àti Èyí Tí Kò Mọ́ Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé, Ẹ sọ fún àwọn ara Ísírẹ́lì pé, Nínú gbogbo ẹranko tí ń gbé lórí ilẹ̀ àwọn wọ̀nyí ni ẹ le jẹ Gbogbo ẹranko tí pátakò ẹsẹ̀ rẹ̀ bá là tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ  Àwọn mìíràn wà tó ń jẹ àpọ̀jẹ nìkan Àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé pátakò ẹsẹ̀ wọn nìkan ni ó là, ìwọ̀nyí ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ fún àpẹrẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ràkunmí ń jẹ àpọ̀jẹ kò ya pátakò ẹsẹ̀, àìmọ́ ni èyí jẹ́ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gára ń jẹ apojẹ àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ehoro ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n kò ya pátakò ẹsẹ̀ àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹdẹ́ ya pátakò ẹṣẹ̀ ṣùgbọ́n kì í jẹ àpọ̀jẹ àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín Ẹ má ṣe jẹ ẹran wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn Àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín  Nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá tí ń gbé inú omi òkun, àti nínú odò èyíkéyí tí ó bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ́ Ṣùgbọ́n nínú gbogbo ẹ̀dá tí ń gbé inú òkun àti nínú odò tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́, yálà nínú gbogbo àwọn tí ń rákò tàbí láàrin gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè yòókù tí ń gbé inú omi àwọn ni kí ẹ kórìíra Nígbà tí ẹ ti kórìíra wọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn ẹ gbọdọ̀ kórìíra òkú wọn Ohunkóhun tí ń gbé inú omi tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́ gbọdọ̀ já sí ìríra fún yín  Àwọn ẹyẹ wọ̀nyí ni ẹ gbọdọ̀ kórìíra tí ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ wọ́n torí pé ohun ìríra ni wọ́n idì, oríṣìiríṣìi igun, Àwòdì àti onírúurú àṣá, Onírúurú ẹyẹ ìwò, Òwìwí, onírúurú ògòǹgò, onírúurú ẹ̀lúùlú, onírúurú àwòdì, Òwìwí kéékèèkéé, onírúurú òwìwí, Òwìwí funfun àti òwìwí ilẹ̀ pápá, àkàlàmàgbò, akọ, onírúurú oódẹ, atọ́ka àti àdán  Gbogbo kòkòrò tí ń fò tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn ni wọ́n jẹ́ ìríra fún yín irú àwọn kòkòrò oníyẹ́ tí wọn sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tí ẹ le Jẹ nìyí Àwọn kòkòrò tí wọ́n ní ìsẹ́po ẹsẹ̀ láti máa fi fò lórí ilẹ̀ Nínú àwọn wọ̀nyí ni ẹ lè jẹ onírúurú esú, onírúurú ìrẹ̀ àti onírúurú tata Ṣùgbọ́n gbogbo kòkòrò oníyẹ́ yóòkù tí ó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin ni kí ẹ kórìíra  Nípa àwọn wọ̀nyí ni ẹ le fi sọ ara yín di àìmọ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́  Àwọn ẹranko tí pátakò wọn kò là tan tàbí tí wọn kò jẹ àpọ̀jẹ jẹ́ àìmọ́ fún yín Ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú èyíkéyí nínú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ Nínú gbogbo ẹranko tí ń fi ẹṣẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tí ń fi èékánná wọn rìn jẹ́ aláìmọ́ fún yín Ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ Ẹni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ Wọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín  Nínú gbogbo ẹranko tí ń rìn lórí ilẹ̀ ìwọ̀nyí ni ó jẹ́ àìmọ́ fún yín Asé, eku àti orísirísi aláǹgbá, Ọmọnílé, alágẹmọ, agílíńtí, ìgbín àti ọ̀gà Nínú gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ìwọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ Bí ọ̀kan nínú wọn bá kú tí wọ́n sì bọ́ sórí nǹkan kan, bí ó ti wù kí irú ohun náà wúlò tó, yóò di aláìmọ́ yálà aṣọ ni a fi ṣe é ni tàbí igi, irun tàbí awọ, ẹ sọ ọ́ sínú omi yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ lẹ́yìn náà ni yóò tó di mímọ́ Bí èyíkéyí nínú wọn bá bọ́ sínú ìkòkò amọ̀, gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ti di àìmọ́ Ẹ gbọdọ̀ fọ ìkòkò náà Bí omi inú ìkòkò náà bá dà sórí èyíkeyí nínú oúnjẹ tí ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ náà di aláìmọ́ Gbogbo ohun mímu tí a lè mú jáde láti inú rẹ̀ di àìmọ́ Gbogbo ohun tí èyíkéyìí nínú òkú wọn bá já lé lórí di àìmọ́ Yálà ààrò ni tàbí ìkòkò ìdáná wọn gbọdọ̀ di fífọ́ Wọ́n jẹ́ àìmọ́ Ẹ sì gbọdọ̀ kà wọ́n sí àìmọ́ Bí òkú wọn bá bọ́ sínú omi tàbí kànga tó ní omi nínú, omi náà kò di aláìmọ́ ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá yọ òkú wọn jáde tí ó fi ọwọ́ kàn-án yóò di aláìmọ́ Bí òkú ẹranko wọ̀nyí bá bọ́ sórí ohun ọ̀gbìn tí ẹ fẹ́ gbìn wọ́n sì jẹ́ mímọ́ Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ti da omi sí ohun ọ̀gbìn náà tí òkú wọn sì bọ́ sí orí rẹ̀ àìmọ́ ni èyí fún un yín  Bí ẹran kan bá kú nínú àwọn tí ẹ lè jẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú rẹ̀ yóò dí aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èyíkéyí nínú òkú ẹranko náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú ẹranko yóò fọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wà ní àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́  Ìríra ni gbogbo ohun tí ń rìn kákiri lórí ilẹ̀ jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ń rìn ká orí ilẹ̀ yálà ó ń fàyàfà tàbí ó ń fi ẹṣẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, tàbí ó ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣẹ̀ rìn ìríra ni èyí Ẹ má ṣe sọ ara yín di aláìmọ́ nípa èyíkéyí nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá wọ̀nyí Ẹ má ṣe sọ ara yín dí àìmọ́ yálà láti ara wọn, tàbí nípaṣẹ̀ wọn Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ torí pé mo jẹ́ mímọ́ Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípaṣẹ̀ ohunkóhun tí ń rìn kákiri lórí ilẹ̀ Èmi ni Olúwa tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín torí náà, ẹ jẹ́ mímọ́ torí pé mímọ́ ni èmi  Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹranko, ẹyẹ, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi àti àwọn ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀ Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrin àìmọ́ àti mímọ́ láàrin ẹ̀dá alààyè, tí ẹ le jẹ àti èyí tí ẹ kò le jẹ   Ìwẹ̀nùmọ́ Lẹ́yìn Ìbímọ Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé Obìnrin tí ó bá lóyún tí ó sì bí ọmọkùnrin, yóò wà láìmọ́ fún ọjọ́ méje bí ìgbà tí ó wà ní ipò àìmọ́ lákókò nǹkan oṣù rẹ̀ Ní ọjọ́ kẹjọ ni kí ẹ kọ ọmọ náà ní ilà Obìnrin náà yóò sì dúró fún ọjọ́ mẹ́talélọ́gbọ̀n láti di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ Kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan ohunkóhun tí ó jẹ́ mímọ́ tàbí kí ó lọ sí ibi mímọ́ Olúwa títí di ọjọ́ tí ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ yóò kọjá Bí ó bá ṣe obìnrin ni ó bí, fún ọ̀sẹ̀ méjì ni obìnrin náà yóò fi wà ní ipò àìmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ Ó sì gbọdọ̀ dúró ní ọjọ́ mẹ́rìndínláàdọ́rin láti di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀  Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ fún ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin bá kọjá kí ó mú ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan wá fún àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ẹbọ sísun àti ọmọ ẹyẹlé tàbí àdàbà kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Ó gbọdọ̀ fi wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa láti ṣe ètùtù fún obìnrin náà lẹ́yìn náà ni yóò di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀  Ìwọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún obìnrin tí ó bá bí ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin Bí kò bá lágbára àti fi àgùntàn ṣe é, ó gbọdọ̀ le mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti èkejì fún ẹbọ sísun Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un Òun yóò sì di mímọ́   Àwọn Òfin Fún Àwọn Ààrùn Ara Tí Ó Le Ràn Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé, Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìwú, èélá tàbí àmì dídán kan ní ara rẹ̀, èyí tí ó le di àìsàn àwọ̀ ara tí ó le ràn ká Ẹ gbọdọ̀ mú-un tọ́ Árónì àlùfáà lọ tàbí sí ọ̀dọ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó jẹ́ àlùfáà Àlùfáà náà ni ó gbọdọ̀ yẹ egbò ara rẹ̀ wò bí irun egbò náà bá di funfun tí egbò náà sì dà bí i pé ó jinlẹ̀ kọjá awọ ara èyí jẹ́ àrùn ara tí ó le è ràn Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò kí ó sọ ọ́ di mímọ̀ pé aláìmọ́ ni ẹni náà Bí àpá ara rẹ̀ bá funfun tí ó sì dàbí ẹni pé kò jinlẹ̀ jù awọ ara, tí irun rẹ̀ kò sì yípadà sí funfun kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje Ní ọjọ́ keje ni kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá rí i pé egbò náà wà ṣíbẹ̀ tí kò sì ràn ká àwọ̀ ara, kí ó tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn Ní ọjọ́ keje ni kí àlùfáà tún padà yẹ̀ ẹ́ wò, bí egbò náà bá ti san tí kò sì ràn ká awọ ara rẹ̀ Kí àlùfáà pè é ní mímọ́ Kí ọkùnrin náà fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì mọ́ Ṣùgbọ́n bí èélá náà bá ń ràn ká awọ ara rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti fi ara rẹ̀ han àlùfáà láti sọ pé ó ti mọ́ Ó tún gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ hàn níwájú àlùfáà Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí èélá náà bá ràn ká awọ ara rẹ̀, kí àlùfáà fi hàn pé kò mọ́ Àrùn ara tí ń ràn ni èyí Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àrùn awọ ara tí ń ràn yìí ni kí a mú wá sọ́dọ̀ àlùfáà Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí ìwú funfun kan bá wà lára rẹ̀ èyí tí ó ti sọ irun ibẹ̀ di funfun tí a sì rí ojú egbò níbi ìwú náà Àrùn ara burúkú gbáà ni èyí, kí àlùfáà jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò mọ́ kí ó má ṣe ya ẹni náà sọ́tọ̀ fún àyẹ̀wò torí pé aláìmọ́ ni ẹni náà jẹ́ tẹ́lẹ̀ Bí àrùn náà bá ràn yíká gbogbo awọ ara rẹ̀ tí àlùfáà sì yẹ̀ ẹ́ wò, tí ó rí i pé àrùn náà ti gba gbogbo ara rẹ̀ láti orí títí dé ẹṣẹ̀, àlùfáà yóò yẹ̀ ẹ́ wò, bí àrùn náà bá ti ran gbogbo àwọ̀ ara rẹ̀, kí àlùfáà sọ pé ó di mímọ́, torí pé gbogbo ara ẹni náà ti di funfun, ó ti mọ́ Ṣùgbọ́n bí ẹran ara rẹ̀ bá tún hàn jáde Óun yóò di àìmọ́ Bí àlùfáà bá ti rí ẹran ara rẹ̀ kan kí ó pè é ni aláìmọ́ Ẹran ara rẹ̀ di àìmọ́ torí pé ó ní àrùn tí ń ràn Bí ẹran ara rẹ̀ bá yípadà sí funfun, kí o farahan àlùfáà Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí egbò rẹ̀ bá ti di funfun kí àlùfáà pe ẹni náà ni mímọ́ Òun yóò sì di mímọ́ Bí oówo bá mú ẹnikẹ́ni nínú ara rẹ̀ tí ó sì san Tí ìwú funfun tàbí àmì funfun tí ó pọ́n díẹ̀ bá farahàn ní ojú ibi tí oówo náà wà kí ẹni náà lọ sọ fún àlùfáà Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá jinlẹ̀ jù awọ ara rẹ̀ lọ tí irun tirẹ̀ sì ti di funfun kí àlùfáà pe ẹni náà ni aláìmọ́ Àrùn ara tí ó le ràn ló yọ padà lójú oówo náà Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí kò sì sí irun funfun níbẹ̀ tí ó sì ti gbẹ kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje Bí ó bá ràn ká awọ ara, kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́ Àrùn tí ó ń ràn ni èyí Ṣùgbọ́n bí ojú ibẹ̀ kò bá yàtọ̀, tí kò sì ràn kára èyí jẹ́ àpa oówo lásán kí àlùfáà pe ẹni náà ni mímọ́ Bí iná bá jó ẹnìkan tí àmì funfun àti pupa sì yọ jáde lójú egbò iná náà Kí àlùfáà yẹ ojú ibẹ̀ wò Bí irun ibẹ̀ bá ti di funfun tí ó sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lásán lọ, àrùn tí ń ràn ká ti wọ ojú iná náà, kí àlùfáà pè é ní aláìmọ́ Àrùn tí ń ran ni ni èyí Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí kò sí irun funfun lójú egbò náà tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí ó sì ti gbẹ, kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje Kí àlùfáà yẹ ẹni náà wò ní ọjọ́ keje, bí ó bá ń ràn ká àwọ̀ ara, kí àlùfáà kí ó pè é ní aláìmọ́ Àrùn ara tí ń ràn ni èyí Ṣùgbọ́n bí ojú iná náà kò bá yípadà tí kò sì ràn ká àwọ̀ ara Ṣùgbọ́n tí ó gbẹ ìwú lásán ni èyí láti ojú iná náà kí àlùfáà pè é ní mímọ́ Ojú àpá iná lásán ni Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ní egbò lórí tàbí ní àgbọ̀n Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí ó bá jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí irun ibẹ̀ sì pọ́n fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tí kò sì kún kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́ làpálàpá ni èyí Àrùn tí ń ràn ká orí tàbí àgbọ̀n ni Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ egbò yìí wò tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí kò sì sí irun dúdú kan níbẹ̀ Kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje Ní ọjọ́ kéje kí àlùfáà yẹ ojú ibẹ̀ wò, bí làpálàpá náà kò bá ràn mọ́ tí kò sì sí irun pípọ́n fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ nínú rẹ̀ tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ Kí a fá gbogbo irun rẹ̀ ṣùgbọ́n kí ó dá ojú àpá náà sí, kí àlùfáà sì tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn Kí àlùfáà yẹ làpálàpá náà wò, ní ọjọ́ kéje bí kò bá ràn ká gbogbo àwọ̀ ara tí kò sì jinlẹ̀ ju inú àwọ̀ ara lọ Kí àlùfáà pè é ní mímọ́ Kí ó fọ aṣọ rẹ̀ òun yóò sì mọ́ Ṣùgbọ́n bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara rẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fi hàn pé ó ti mọ́ Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara kí àlùfáà má ṣe yẹ irun pupa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ wò mọ́ Ẹni náà ti di aláìmọ́ Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdájọ́ àlùfáà pé ẹni náà kò mọ́, tí ojú làpálàpá náà kò bá yípadà, tí irun dúdú si ti hù jáde lójú rẹ̀ Làpálàpá náà ti san Òun sì ti di mímọ́ Kí àlùfáà fi í hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti di mímọ́ Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ní ojú àpá funfun lára àwọ̀ ara rẹ̀ Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ojú àpá náà bá funfun àrùn ara tí kò léwu ni èyí tí ó farahàn lára rẹ̀ Ẹni náà mọ́ Bí irun ẹnìkan bá rẹ̀ dànù tí ó sì párí Ẹni náà mọ́ Bí irun ẹnìkan bá rẹ̀ dànù níwájú orí tí ó sì párí níwájú orí Ẹni náà mọ́ Ṣùgbọ́n bí ó bá ní egbò pupa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ní ibi orí rẹ̀ tí ó pá, tàbí níwájú orí rẹ̀ àrùn tí ń ràn ká iwájú orí tàbí ibi orí ni èyí Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí egbò tó wù níwájú orí rẹ̀ tàbí tí orí rẹ̀ bá pupa díẹ̀ tí ó dàbí àrùn ara tí ń ràn kálẹ̀ Alárùn ni ọkùnrin náà kò sì mọ́, kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́ torí egbò tí ó wà ní orí rẹ̀ Kí ẹni tí àrùn náà wà ní ara rẹ̀ wọ àkísà Kí ó má ṣe gé irun rẹ̀, kí ó daṣọ bo ìṣàlẹ̀ ojú rẹ̀ kí ó sì máa ké wí pé, Aláìmọ́! Aláìmọ́! Gbogbo ìgbà tí àrùn náà bá wà ní ara rẹ̀ aláìmọ́ ni kí ó máa dá gbé Kí ó máa gbé lẹ́yìn ibùdó Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá ba aṣọ kan jẹ́ yálà aṣọ onírun àgùtàn tàbí aṣọ funfun Ìbáà ṣe títa tàbí híhun tí ó jẹ́ aṣọ funfun tàbí irun àgùtàn, bóyá àwọ̀ tàbí ohun tí a fi àwọ̀ ṣe Bí ìbàjẹ́ ara aṣọ ìbáà ṣe awọ, irun àgùtàn, aṣọ títa, aṣọ híhun tàbí ohun tí a fi awọ ṣe bá di aláwọ̀ ewé tàbí kí ó pupa èyí jẹ́ ẹ̀tẹ̀ tí ń ràn ká Ẹ gbọdọ̀ fi hàn fún àlùfáà Àlùfáà yóò yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, yóò sì pa gbogbo ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà ti ràn mọ́ fún ọjọ́ méje Ní ọjọ́ keje kí ó yẹ̀ ẹ́ wò bí àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ràn ká ara aṣọ tàbí irun àgùtàn, aṣọ híhun tàbí awọ, bí ó ti wù kí ó wúlò tó, ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí jẹ́, irú ohun bẹ́ẹ̀ kò mọ́ Ó gbọdọ̀ sun aṣọ náà tàbí irun àgùtàn náà, aṣọ híhun náà tàbí awọ náà ti ó ni ìbàjẹ́ kan lára rẹ̀ ni iná torí pé ẹ̀tẹ̀ tí í pa ni run ni Gbogbo nǹkan náà ni ẹ gbọdọ̀ sun ní iná Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí ẹ̀tẹ̀ náà kò ràn ká ara aṣọ náà yálà aṣọ títa, aṣọ híhun tàbí aláwọ Kí ó pàṣe pé kí wọ́n fọ ohunkóhun tí ó bàjẹ́ náà kí ó sì wà ní ìpamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn Lẹ́yìn tí ẹ bá ti fọ ohun ti ẹ̀tẹ̀ náà mú tan, kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí ẹ̀tẹ̀ náà kò bá yí àwọn aṣọ náà padà, bí kò tilẹ̀ tí ì ràn Àìmọ́ ni ó jẹ́ Ẹ fi iná sun un, yálà ẹ̀gbẹ́ kan tàbí òmíràn ní ẹ̀tẹ̀ náà dé Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò ti ẹ̀tẹ̀ náà bá ti kúrò níbẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fọ̀ ohunkóhun tí ó mú, kí ó ya ibi tí ó bàjẹ́ kúrò lára aṣọ náà, awọ náà, aṣọ híhun náà tàbí aṣọ tìta náà Ṣùgbọ́n bí ó bá tún ń farahàn níbi aṣọ náà, lára aṣọ títa náà, lára aṣọ híhun náà tàbí lára ohun èlò awọ náà, èyí fi hàn pé ó ń ràn ká Gbogbo ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà bá wà lára rẹ̀ ni kí ẹ fí iná sun Aṣọ náà, aṣọ títa náà, aṣọ híhun náà tàbí ohun èlò àwọ náà tí a ti fọ̀ tí ó sì mọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tẹ̀ náà ni kí a tún fọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i Yóò sì di mímọ́ Ìlànà wọ̀nyí wà fún àwọn ohun tí ẹ̀tẹ̀ bàjẹ́ níbi, aṣọ irun àgùtàn aṣọ funfun, aṣọ títa, aṣọ híhun tàbí ohun èlò awọ, láti fi hàn bóyá wọ́n wà ní mímọ́ tàbí àìmọ́ Ìwẹ̀nùmọ́ Kúrò Nínú Àrùn Ẹ̀tẹ̀ Tó Mú Awọ Ara Olúwa sọ fún Mósè pé, Èyí ni àwọn ìlànà fún ẹni tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ní àkókò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, bí a bá mú-un tọ àlùfáà wá Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò ní ẹ̀yìn ibùdó bí ara rẹ̀ bá ti yá kúrò nínú àrùn ẹ̀tẹ̀ náà Kí àlùfáà páṣẹ pé kí a mú ààyè ẹyẹ mímọ́ méjì, igi sídà, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù wá fún ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́ Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọn pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ tó wà nínú ìkòkò amọ̀ Lẹ́yìn náà kí ó ri ààyè ẹyẹ pẹ̀lú igi sídà, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a ti pa sínú omi náà Ìgbà méje ni kí o wọ́n omi yìí sí ara ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́ kúrò nínú àrùn ara náà kí ó ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ níta gbangba Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́ Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ kéje irun orí rẹ̀, irungbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tó kù Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́ Ní ọjọ́ kejọ kí ó mú àgbò méjì àti abo ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí wọn kò ní àlébù wá, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí à pò pọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ àti òsùwọ̀n òróró kan Àlùfáà tí ó pè é ní mímọ́ yóò mú ẹni náà tí a ó sọ di mímọ́ àti ọrẹ rẹ̀ wá ṣíwájú Olúwa ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé Kí àlùfáà mú ọ̀kan nínú àwọn àgbò àti òróró kí ó sì fi rú ẹbọ ẹbí Kí ó sì fí wọn níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífí Kí ó pa àgbò náà ní ibi mímọ́ nibi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun Bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi náà jẹ́ ti àlùfáà ó jẹ́ mímọ́ jùlọ Kí àlùfáà mú nínú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi náà kí ó fi sí etí ọ̀tún ẹni náà tí a ó wẹ̀ mọ́, kí ó tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti orí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ Àlùfáà yóò sì mú díẹ̀ nínú òróró, yóò sì dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀ Yóò sì ti ìka ìfábẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ bọ inú òróró àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, yóò sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ níwájú Olúwa nígbà méje Àlùfáà yóò mú lára òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ yóò fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí à ó wẹ̀ mọ́ Àlùfáà yóò fi òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí a ó wẹ̀ mọ́, yóò sì ṣe ètùtù fún un níwájú Olúwa Àlùfáà yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ yóò ṣe ètùtù fún ẹni tí a ó wẹ̀ kúrò nínú àìmọ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà àlùfáà yóò pa ẹran ọrẹ ẹbọ sísun Yóò sì rú u lórí pẹpẹ pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, yóò sì ṣe ètùtù fún un Òun yóò sì di mímọ́ Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹbí, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò pọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òṣùwọ̀n òróró àti àdàbà méjì tàbí ẹyẹlé méjì èyí tí agbára rẹ̀ ká ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun Kí ó mú wọn wá ní ọjọ́ kẹjọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ ṣíwájú àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa Àlùfáà náà yóò sì mú ọ̀dọ́ àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú òróró yóò sì fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì Kí ó pa ọ̀dọ́ àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi kí ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ Kí ó fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún Àlùfáà yóò sì da díẹ̀ lára òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ osì ara rẹ̀ Yóò sì fi ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ wọ́n òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀ nígbà méje níwájú Olúwa Àlùfáà yóò sì mú lára òróró ọwọ́ rẹ̀ sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹṣẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ní ibi kan náà tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi sí Kí àlùfáà fi ìyókù nínú òróró ọwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni náà tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún láti ṣe ètùtù fún un ní ìwájú Olúwa Lẹ́yìn náà kí ó fí àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rúbọ níwọn ti agbára rẹ̀ mọ Ọ̀kan fún ẹbọ ẹṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù níwájú Olúwa ní ìpò ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́ Òfin nìyí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àrùn ara tí ó le ran tí kò sì lágbára láti rú ẹbọ tí ó yẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ bí a ti fi lélẹ̀ Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kénánì tí mo fi fún yín ni ìní, tí mo sì fí àrùn ẹ̀tẹ̀ sínú ile kan ní ilẹ̀ ìní yín Kí ẹni tí ó ní ilọ̀ náà lọ sọ fún àlùfáà pé, Èmi tí rí ohun tí ó jọ àrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má báà di àìmọ́ Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò Yóò yẹ àrùn náà wò, bí àrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa àmì àwọ̀ ewé tàbí àmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ Àlùfáà yóò jáde kúrò nínú ilé náà, yóò sì ti ilẹ̀kùn ilé náà pa fún ọjọ́ méje Àlùfáà yóò padà wá yẹ ilé náà wò ní ọjọ́ keje Bí àrùn náà bá ti tàn ká ara ògiri Àlùfáà yóò pàṣẹ kí a yọ àwọn òkúta tí àrùn náà ti bàjẹ́ kúrò kí a sì kó wọn dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú Yóò sì mú kí wọ́n ha ògiri inú ilé náà yíká Gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà tí ó ti ha ni kí wọ́n kó dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú náà Òkúta mìíràn ni kí wọ́n fi dípò àwọn tí a ti yọ dànù kí wọ́n sì rẹ́ ilé náà pẹ̀lú àwọn ohun ìrẹ́lé tuntun Bí àrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí àrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́ Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́ Ẹni tí ó bá wọ inú ilé náà lẹ́yìn tí a ti tì í, yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ Ẹni tí ó bá sùn nínú ilé náà tàbí tí ó bá jẹun nínú rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ Bí àlùfáà bá wá yẹ̀ ẹ́ wò tí àrùn náà kò gbilẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí a ti rẹ́ ilé náà kí àlùfáà pe ilé náà ní mímọ́, torí pé àrùn náà ti lọ Láti sọ ilé yìí di mímọ́ Àlùfáà yóò mú ẹyẹ méjì àti igi sídà òdòdó àti hísópù Yóò sì pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sorí omi tí ó mọ́ nínú ìkòkò amọ̀ Kí ó ri igi sídà, hísópù, òdòdó àti ààyè ẹyẹ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ òkú ẹyẹ àti omi tí ó mọ́ náà kí ó fi wọ́n ilẹ náà lẹ́ẹ̀méje Yóò fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà, omi tí ó mọ́, ààyè ẹyẹ, igi sídà, hisopu àti òdòdó sọ ilé náà di mímọ́ Kí àlùfáà ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ lẹ́yìn ìlú Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ilé náà Ilé náà yóò sì mọ́ Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún èyíkéyí àrùn àwọ̀ ara tí ó le è ràn ká , fún làpálàpá, fún ẹ̀tẹ̀ nínú aṣọ, tàbí ilé, fún ìwú, fún èélá àti ibi ara dídán Láti mú kí a mọ̀ bóyá nǹkan mọ́ tàbí kò mọ́ Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún àrùn àwọ̀ ara tí ó ń ràn ká àti ẹ̀tẹ̀ Ìṣunjáde láti inú ara ti ń sọni di aláìmọ́ Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé Ẹ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kí ẹ wí fún wọn pé Bí ìṣunjáde bá ń jáde lára ọkùnrin kan lójú ara ìṣunjáde náà jẹ́ àìmọ́ Yálà ó ń jáde léraléra tàbí ó dúró, èyí yóò sọ ọ́ di aláìmọ́ Báyìí ni ìṣunjáde rẹ̀ ṣe le è sọ ọ́ di aláìmọ́  Gbogbo ibùsùn tí irú ẹni tí ó ní ìṣunjáde náà bá sùn di àìmọ́ Bí ẹnikẹ́ni bá fi ara kan ibùsùn rẹ̀, ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá joko lórí ohunkóhun tí ọkùnrin tí ó ní ìṣunjáde bá jókòó le gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀, kí ó sì wà láìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́  Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin náà tí ó ní ìṣunjáde gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́  Bí ẹni tí ó ní ìṣunjáde bá tu itọ́ sí ẹni tí ó mọ́ lára, ẹni tí ó mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ yóò sì wà nípò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́  Gàárì ẹranko tí ẹni náà bá gùn yóò di àìmọ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó wà lábẹ́ ọkùnrin náà di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ ara rẹ̀ Yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́  Ẹnikẹ́ni tí ọkùnrin tí ó ní ìṣunjáde ní ara rẹ̀ bá farakàn láì fi omi fọ ọwọ́ rẹ̀, gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́  Ìkòkò amọ̀ tí ọkùnrin náà bá fọwọ́ kàn ni kí ẹ fọ́, gbogbo ohun èlò igi tí ó fọwọ́ kàn ni kí ẹ fi omi sàn  Ẹnikẹ́ni tí a bá wẹ̀ nù kúrò nínú ìṣunjáde rẹ̀ gbọdọ̀ ka ọjọ́ méje fún àwọn ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀ yóò sì di mímọ́ Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, kí ó sì wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa , kí ó sì kó wọn fún àlùfáà Kí àlùfáà fi wọ́n rúbọ ọ̀kan fún ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ọrẹ ẹbọ sísun níwájú Olúwa ní ipò ọkùnrin náà nítorí ìṣunjáde rẹ̀  Bí nǹkan ọkùnrin kan bá tú jáde, kí ó wẹ gbogbo ara rẹ̀ kí ó wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ Yálà àwọ̀ tàbí aṣọ tí nǹkan ọkùnrin bá dà sí lórí ni kí ẹ fọ̀ yóò sì wà ní ipò àìmọ́ di ìròlẹ́ Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin lòpọ̀ tí nǹkan ọkùnrin sì tú jáde lára rẹ̀ Àwọn méjèèjì gbọdọ̀ fi omi wẹ̀ kí wọ́n sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́  Bí obìnrin bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ obìnrin yìí wà ní àìmọ́ títí di ọjọ́ méje Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan an yóò wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́  Gbogbo ohun tí ó bá sùn lé ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ di àìmọ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ibùsùn rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó bá jókòó lé gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ Ìbáà se ibùsùn tàbí ohunkóhun tí ó jókòó lé Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóò jẹ̀ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ̀  Bí ọkùnrin kan bá bá a lòpọ̀ tí nǹkan osù rẹ̀ sì kàn án lára, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, gbogbo ibùsùn tí ọkùnrin náà bá sùn yóò jẹ́ aláìmọ́  Bí obìnrin bá ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọjọ́ púpọ̀ yálà sí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tàbí tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá kọjá ìgbà tí ó yẹ Gbogbo ìgbà tí ó bá fi ń ní ìsun ẹ̀jẹ̀ náà ni yóò fi wà ní àìmọ́ gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ Ibùsùn tí ó wù kí ó sùn sí ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀jẹ̀ náà ń wá yóò jẹ́ àìmọ́ bí ibùsùn rẹ̀ ṣe jẹ́ lákókò nǹkan oṣù rẹ̀ Gbogbo ohun tí ó bá jokòó lé yóò wà ní àìmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn wọ́n yóò wà ní àìmọ́ Ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ kí ó sì wà ní àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́  Nígbà tí ó bá di mímọ́ kúrò nínú ìsun rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ méje lẹ́yìn náà, a ó kà á sí mímọ́ Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé wá ṣíwájú àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé Kí àlùfáà fi ọ̀kan rúbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún un, níwájú Olúwa fún àìmọ́ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀  Ẹ ya ará Ísírẹ́lì sọ́tọ̀ kúrò nínú ohun tí ó ń sọ wọ́n di aláìmọ́ kí wọ́n má báa kú nínú àìmọ́ wọn nípa bíba ibùgbé mímọ́ mi jẹ́ Èyí tí ó wà láàrin wọn   Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún ọkùnrin tí ó ni ìṣunjáde fún ẹnikẹ́ni tí a sọ di àìmọ́ nípa ìṣunjáde nǹkan ọkùnrin rẹ̀ Fún obìnrin ní nǹkan oṣù rẹ̀, fún ọkùnrin tàbi obìnrin tí ó ní ìṣunjáde, àti fún ọkùnrin tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin tí ó jẹ́ aláìmọ́ Ọjọ́ Ètùtù Ìwẹ̀nùmọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Gbogbo Olúwa sọ fún Mósè lẹ́yìn ikú àwọn ọmọ Árónì méjèèje tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n súnmọ́ Olúwa Olúwa sì sọ fún Mósè pé Kìlọ̀ fún Árónì arákùnrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wá nígbà gbogbo sí ibi mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa ní ibi tí àpótí ẹ̀rí àti ìtẹ́ àánú wà, kí ó má baà kú nítorí pé Èmi ó farahàn nínú ìkùùkuu lórí ìtẹ́ àánú Báyìí ni Árónì yóò ṣe máa wá sí ibi mímọ́ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò fún ẹbọ sísun Òun yóò sì wọ aṣọ funfun mímọ́ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ funfun, yóò sì fi àmùrè funfun mímọ́ dì í yóò sì dé fìlà funfun àwọn aṣọ mímọ́ nìwọ̀nyí Òun yóò sì fi omi wẹ̀, kí ó tó wọ̀ wọ́n Òun yóò sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì láti ọ̀dọ̀ gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fi ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n àti àgbò kan fún ẹbọ sísun Árónì yóò sì fi akọ màlúù rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ èyí tí ṣe ti ara rẹ̀ òun yóò sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ Lẹ́yìn náà yóò sì mú ewúrẹ́ méjì náà wá sí iwájú Olúwa ní ibi ilẹ̀kùn àgọ́ ìpàdé Árónì yóò sì dìbò ní ti àwọn ewúrẹ́ méjèèje náà ìbò àkọ́kọ́ fún ti Olúwa , àti èkejì fún ewúrẹ́ ìpààrọ̀ Árónì yóò sì mú ewúrẹ́ tí ìbò Ọlọ́run mú, yóò sì fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Ṣùgbọ́n ewúrẹ́ tí ìbò bá mú gẹ́gẹ́ bí ewúrẹ́ ìpààrọ̀ ni a ó mú wá láàyè ṣíwájú Olúwa láti fi ṣe ètùtù sí i àti láti jẹ́ kí ó lọ lọ́fẹ̀ẹ́, sí ihà Árónì yóò sì mú akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ Yóò sì pa akọ màlúù náà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ Yóò sì mú àwo tùràrí tí ó kún fún èédú tí a ti sun pẹ̀lú iná láti orí pẹpẹ wá ṣíwájú Olúwa àti ẹ̀kúnwọ́ méjì tùràrí tí a gún kúnná yóò sì mú un wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa Yóò sì fi tùràrí náà lé orí iná níwájú Olúwa kí èéfín tùràrí náà baà le bo ìtẹ́ àánú tí ó wà ní orí àpótí ẹ̀rí kí o má baà kú Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù náà yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn, ní iwájú ìtẹ́ àánú, yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn nígbà méje níwájú ìtẹ́ àánú Nígbà yìí ni yóò pa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà fún àwọn ènìyàn yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa, bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà ni yóò ṣe ti ewúrẹ́ yìí, yóò sì wọ́n ọn sórí ìtẹ́ ètùtù àti ṣíwájú ìtẹ́ ètùtù Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ibi mímọ́ jùlọ nítorí àìmọ́ àwọn ará Ísírẹ́lì àti nítorí gbogbo ìrékọjá wọn àti ìṣọ̀tẹ̀ wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbogbo, bákan náà ni yóò sì ṣe fún àgọ́ ìpàdé, èyi tí ó wà láàrin wọn nínú àìmọ́ wọn Kí ó má ṣe sí ẹyọ ènìyàn kan nínú àgọ́ ìpàdé nígbà tí òun bá wọ ibi mímọ́ lọ láti ṣe ètùtù títí di ìgbà tí yóò fi jáde lẹ́yìn tí ó ba ṣe ètùtù fúnrarẹ̀ fún ìdílé rẹ̀ àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ Ísírẹ́lì Lẹ́yìn náà òun yóò lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú Olúwa yóò sì ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti nínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà, yóò sì fi sí orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwo pẹpẹ náà yíká Lẹ́yìn náà òun yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sórí rẹ̀ pẹ̀lú ìka rẹ̀ nígbà méje láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ àti láti sọ ọ́ dí mímọ́ kúrò nínú àìmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Lẹ́yìn ti Árónì ti parí ṣíṣe ètùtù ti ibi mímọ́ jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá Árónì yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Ísírẹ́lì lée lórí gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà Yóò sì rán an lọ sí aṣálẹ̀ láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedédé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé Òun yóò sì tú ewúrẹ́ náà sílẹ̀ ní àṣálẹ́ Árónì yóò sì padà wá sí ibi àgọ́ ìpàdé yóò sì bọ́ aṣọ funfun gbòò tí ó wọ̀ nígbà tí ó lọ sí ibi mímọ́ jùlọ yóò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀ Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn Òun yóò sì sun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà lórí pẹpẹ Ẹni tí ó tú ewúrẹ́ ìpààrọ̀ náà sílẹ̀ yóò sì fọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi lẹ́yìn èyí ó lè wá sí ibùdó Ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sí ibi mímọ́ jùlọ ni kí a gbe jáde kúrò ní ibùdó Awọ wọn ni a ó fi iná sun bákan náà Ẹni tí ó sun wọ́n yóò sì fọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wẹ ara rẹ̀ lẹ́yìn èyí ni ó tó le wọ ibùdó Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún yín pé ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ni ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan, yálà onílé tàbí àlejò tí ó ń gbé pẹ̀lú yín Torí pé ní ọjọ́ yìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún yín láti sọ yín di mímọ́ kí ẹ̀yin baà le mọ́ níwájú Olúwa yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo Ọjọ́ yìí yóò jẹ́ ọjọ́ ìsinmi pátapáta fún un yín ẹ̀yin yóò sì ṣẹ́ ara yín Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé Àlùfáà náà tí a ti fí òróró yàn tí a sì ti sọ di mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ilé ìsìn nípò bàbá rẹ̀ òun ni kí ó ṣe ètùtù yóò sì wọ aṣọ funfun gbòò àní aṣọ mímọ́ náà òun yóò sì ṣe ètùtù Yóò sì ṣe ètùtù fún àgọ́ ìpàdé àti fún pẹpẹ yóò sì ṣe ètùtù fún àlùfáà àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ènìyàn náà Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún yín láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ará Ísírẹ́lì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́dún Ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Ẹ̀jẹ̀ Jíjẹ Jẹ́ Èèwọ̀ Olúwa sọ fún Mósè pé Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ nìyí Bí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé Ísírẹ́lì bá pa màlúù tàbí ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí àgbò nínú ibùdó tàbí bí ó bá pa á lẹ́yìn ibùdó tí kò sì mú un wá sí ibi àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa níwájú àgọ́ ìpàdé ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni kí ẹ kà sí ẹni náà lọ́rùn torí pé ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ẹni náà ni a ó sì gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì le è máa mú ẹbọ wọn tí wọn ti rú ní ìta gbangba wá sí iwájú Olúwa wọ́n gbọdọ̀ mú un wá ṣíwájú àlùfáà àní sí Olúwa ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé kí wọ́n sì rú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa Àlùfáà náà yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n ibi pẹpẹ Olúwa ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé yóò sì sun ọ̀rá rẹ̀ ní òórùn dídùn sí Olúwa Torí náà, kí wọn má ṣe rú ẹbọ wọn sí ère ẹranko mọ́, nínú èyí tí wọ́n ti ṣe àgbérè tọ̀ lọ Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé láti ìran dé ìran wọn tí ń bọ̀ Kí ó sọ fún wọn pé Ọkùnrin yówù kí ó jẹ́ ní ìdílé Ísírẹ́lì tàbí ti àwọn àlejò tí ń gbé láàrin wọn tí ó bá rú ọrẹ sísun tàbí ṣe ẹbọ tí kò sì mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rúbọ sí Olúwa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀  Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Ísírẹ́lì tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrin wọn Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀ èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ Nítorí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá wà èmi sì ti fi fún yín lórí pẹpẹ fún ètùtù ọkàn yín nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a fi ń ṣe ètùtù fún ẹ̀mí ènìyàn Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀  Ẹnikẹ́ni yálà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàbí àlejò tí ń gbé láàrin wọn, tí ó bá pa ẹranko tàbí ẹyẹ tí ó yẹ fún jíjẹ gbọdọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì bò ó mọ́lẹ̀ Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò  Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó kú sílẹ̀ fúnrarẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko búburú pa kálẹ̀ yálà onílé tàbí àlejò ó ní láti fọ aṣọ rẹ̀ Kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀ yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di àṣálẹ́ lẹ́yìn èyí ni yóò tó di mímọ́ Ṣùgbọ́n bí ó bá kọ̀ láti wẹ ara rẹ̀ tí kò sì fọ aṣọ rẹ̀ náà ẹ̀bi rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀   Ìbálòpọ̀ Tí Kò Bá Òfin Mu Olúwa sọ fún Mósè pé Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní Éjíbítì níbi tí ẹ ti gbé rí bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kénánì níbi tí èmi ń mú yín lọ Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé iṣe wọn Ẹ gbọdọ̀ tẹ̀lé òfin mi kí ẹ sì kíyèsí àti pa àṣẹ mi mọ́ Ẹ pa àṣẹ àti òfin mi mọ́ Ẹni tí ó bá ṣe ìgbọ́ràn sí wọn yóò máa gbé nípa wọn, Èmi ni Olúwa  Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀, èmí ni Olúwa  Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u bàbá rẹ nípa bíbá ìyá rẹ lòpọ̀, ìyá rẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ bá a lòpọ̀  Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u bàbá rẹ nípa bíbá ìyàwó bàbá rẹ lòpọ̀ nítorí ìhòòhò bàbá rẹ ni  Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin rẹ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lòpọ̀, yálà a bí i nílé yín tàbí lóde  Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin, ọmọ rẹ ọkùnrin lòpọ̀ tàbí ọmọbìnrin ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀ nítorí pé ìhòòhò wọn, ìhòòhò ìwọ fúnrarẹ ni  Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin aya bàbá rẹ lòpọ̀ èyí tí a bí fún bàbá rẹ nítorí pé arábìnrin rẹ ni  Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin bàbá rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan bàbá rẹ ni  Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin mọ̀mọ́ rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan ìyá rẹ ni  Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u arákùnrin bàbá rẹ nípa sísun mọ́ aya rẹ̀ láti bá a lòpọ̀ nítorí pé ìyàwó ẹ̀gbọ́n bàbá rẹ ni  Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọ àna obìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé aya ọmọ rẹ ni Má ṣe bá a lòpọ̀  Má ṣe bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ ọkùnrin lòpọ̀ nítorí pé yóò tàbùkù ẹ̀gbọ́n rẹ  Má ṣe bá ìyá àti ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin ọmọbìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan rẹ tímọ́tímọ́ ni nítorí àbùkù ni  Má ṣe fẹ́ àbúrò ìyàwó rẹ obìnrin ní aya gẹ́gẹ́ bí orogún tàbi bá a lòpọ̀, nígbà tí ìyàwó rẹ sì wà láàyè  Má ṣe súnmọ́ obìnrin láti bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù, nítorí àkókò àìmọ́ ni  Ìwọ kò gbọdọ̀ bá aya aládúgbò rẹ lòpọ̀, kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́ pẹ̀lú rẹ̀  Ìwọ kò gbọdọ̀ fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ rúbọ lórí pẹpẹ sí òrìṣà Mólékì, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́ Èmi ni Olúwa  Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọkùnrin lòpọ̀ bí ìgbà tí ènìyàn ń bá obìnrin lòpọ̀ ìríra ni èyí jẹ́  Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀ kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́ Obìnrin kò sì gbọdọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀, ohun tó lòdì ni  Má ṣe fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ba ara rẹ jẹ́, torí pé nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀ èdè tí mo lé kúrò níwájú yín ti ba ara wọn jẹ́ Nítorí pé ilẹ̀ náà di àìmọ́ nítorí náà mo fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ Ilẹ̀ náà sì pọ àwọn olùgbé ibẹ̀ jáde Ṣùgbọ́n kí ẹ máa pa àṣẹ àti òfin mi mọ́ Onílé tàbí àlejò tó ń gbé láàrin yín kò gbọdọ̀ ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun ìríra wọ̀nyí Nítorí pé gbogbo ohun ìríra wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín ti ṣe tí ó sì mú kí ilẹ̀ náà di aláìmọ́ Bí ẹ bá sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́ yóò pọ̀ yín jáde bí ó ti pọ àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ti wá ṣáájú yín jáde  Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ohun ìríra wọ̀nyí, kí ẹ gé irú ẹni náà kúrò láàrin àwọn ènìyàn Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ ṣe ohun tí mo fẹ́, kí ẹ má sì lọ́wọ́ nínú àṣà ìríra wọ̀nyí, tí wọn ń ṣe kí ẹ tó dé Ẹ má ṣe fi wọ́n ba ara yín jẹ́ Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín   Àwọn Onírúurú Òfin Olúwa sọ fún Mósè pé, Bá gbogbo àpéjọpọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, sì wí fún wọn pé Ẹ jẹ́ mímọ́ nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́  Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá àti bàbá rẹ̀, kí ẹ sì ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́ Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín  Ẹ má ṣe yípadà tọ ère òrìsà lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ rọ ère òrìsà idẹ fún ara yín Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín  Nígbà tí ẹ̀yín bá sì rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa , kí ẹ̀yin kí ó se é ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò yín! Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú u náà ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ tàbí ní ọjọ́ kejì èyí tí ó bá sẹ́kù di ọjọ́ kẹta ni kí ẹ fi iná sun Bí ẹ bá jẹ nínú èyí tí ó sẹ́kù di ọjọ́ kẹta, àìmọ́ ni èyí jẹ́, kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù, nítorí pé ó ti ba ohun mímọ́ Olúwa jẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀  Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ sa ẹ̀sẹ́ Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátapáta, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú oko àjàrà yín Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín  Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè  Ìwọ kò gbọdọ̀ parọ́  Ẹ kò gbọdọ̀ tan ara yín jẹ  Ìwọ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́ Èmi ni Olúwa  Ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ aládúgbò rẹ jẹ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ jà á lólè  Ìwọ kò gbọdọ̀ dá owó iṣẹ́ alágbàṣe dúró di ọjọ́ kejì  Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣépè lé adití bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ fi ohun ìdìgbòlù sí iwájú afọ́jú, ṣùgbọ́n bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ Èmi ni Olúwa  Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúṣàájú sí ẹjọ́ talákà bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ  Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olófofó láàrin àwọn ènìyàn rẹ  Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mi aládúgbò rẹ wéwu Èmi ni Olúwa  Ìwọ kò gbọdọ̀ kóríra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládúgbò rẹ wí, kí o má baà jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀  Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san má sì ṣe bínú sí èyíkéyí nínú àwọn ènìyàn rẹ Ṣùgbọ́n, fẹ́ràn aládúgbò rẹ bí ara rẹ, Èmi ni Olúwa  Má a pa àṣẹ mi mọ́  Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ohun ọ̀sìn rẹ máa gùn pẹ̀lú ẹ̀yà mìíràn  Ìwọ kò gbọdọ̀ gbin dàrúdàpọ̀ oríṣìí irúgbìn méjì sínú oko kan  Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ èyí tí a fi oríṣìí ohun èlò ìhunṣọ méjì ṣe  Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin tí ó jẹ́ ẹrú lòpọ̀, ẹni tí a ti mọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn tí a kò sì tí ì rà á padà tàbí sọ ọ́ di òmìnira Ẹ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí kí ẹ sì jẹ wọ́n ní ìyà tó tọ́ ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ pa wọ́n, torí pé kò ì tíì di òmìnira Kí ọkùnrin náà mú àgbò kan wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé bí i ẹbọ ẹ̀bi sí Olúwa Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà níwájú Olúwa fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ A ó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ náà jìn-ní  Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí ẹ sì gbin igi eléso, kí ẹ ká èso wọn bí ohun èèwọ̀ Fún ọdún mẹ́ta ni kí ẹ kà á sí èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ jẹ ẹ́ Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹrin, gbogbo èso wọ̀nyí yóò jẹ́ mímọ́, ọrẹ fún ìyìn Olúwa Ní ọdún karùn ún ni ẹ̀yin tó lè jẹ nínú èso igi náà, kí èso wọn ba à le máa pọ̀ sí i Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín  Ẹ má ṣe jẹ ẹrankẹ́ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀  Ẹ kò gbọdọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ yẹ̀míwò tàbí oṣó  Ẹ má ṣe dá òṣù sí àárin orí yín tàbí kí ẹ ré orí irùngbọ̀n yín bí àwọn aláìkọlà ti ń ṣe  Ẹ má ṣe titorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, Ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan Èmi ni Olúwa  Ẹ má ṣe ba ọmọbìnrin yín jẹ́ láti sọ ọ́ di aṣẹ́wó, kí ilẹ̀ yín má ba à di ti àgbérè, kí ó sì kún fún ìwà burúkú  Ẹ gbọdọ̀ máa pa ìsinmi mi mọ́ kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi, Èmi ni Olúwa  Ẹ má ṣe tọ abókúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́ Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín  Fi ọ̀wọ̀ fún ọjọ́ orí arúgbó kí ẹ sì bọlá fún àwọn àgbàlagbà Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín Èmi ni Olúwa  Nígbà tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín ní ilẹ̀ yín, ẹ má ṣe ṣe é ní ibi kí àjèjì tí ń gbé pẹ̀lú yín dàbí onílé láàrin yín kí ẹ sì fẹ́ràn rẹ̀ bí i ara yín, torí pé ẹ̀yin ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Éjíbítì rí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín  Ẹ má ṣe lo òsùwọ̀n èké, nígbà tí ẹ bá ń díwọ̀n yálà nípa òsùwọ̀n ọ̀pá, òsùwọ̀n ìwúwo tàbí òsùwọ̀n onínú Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òsùwọ̀n yín òsùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òsùwọ̀n wíwúwo, òsùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òsùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì  Ẹ ó sì máa pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n Èmi ni Olúwa   Ọrẹ ohun jíjẹ  Bí ẹnìkan bá mú ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ wá fún Olúwa ọrẹ rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun darádara, kí ó da òróró sí i, kí o sì fi tùràrí sí i, kí ó sì gbé lọ fún àwọn ọmọ Árónì tí í se àlùfáà Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ìyẹ̀fun àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí kí ó sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ọrẹ tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí Olúwa Ìyòókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ náà jẹ́ ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ ìpín tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa  Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ, èyí tí a yan lórí ààrò iná, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúná dáradára, àkàrà tí a se láì ní ìwúkàrà, tí a sì fi òróró pò àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a ṣe láì ní ìwúkàrà èyí tí a fi òróró pò Bí ó bá jẹ́ inú àwo pẹẹrẹ ni o ti se ohun jíjẹ rẹ, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára tí a fi òróró pò, kò sì gbọdọ̀ ní ìwúkàrà Rún un kí o sì da òróró síi lórí, ọrẹ ohun jíjẹ ni Bí ó bá jẹ́ inú páànù ni o ti se ọrẹ ohun jíjẹ rẹ, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára àti òróró Mú ọrẹ ohun jíjẹ tí a fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe wá fún Olúwa gbé e fún àlùfáà, ẹni tí yóò gbe e lọ sí ibi pẹpẹ, Àlùfáà yóò sì mú ẹbọ ìrántí nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí, yóò sì sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa Ìyòókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí jẹ́ ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ èyí tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa  Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ tí ẹ bá mú wá fún Olúwa kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà nínú, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ sun ohun wíwú tàbí oyin nínú ọrẹ tí ẹ fi iná sun sí Olúwa Ẹ lè mú wọn wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àkọ́so ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ mú wọn wá sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn Ẹ fi iyọ̀ dun gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ yín Ẹ má se aláì fi iyọ̀ májẹ̀mu Ọlọ́run yín sínú àwọn ọrẹ ohun jíjẹ yín, ẹ fi iyọ̀ sí gbogbo ọrẹ yín  Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ ti àkọ́so oko yín wá fún Olúwa kí ẹ mú ọkà túntún tí a fi iná yan Kí ẹ da òróró lé e lórí, kí ẹ sì fi tùràrí sí i, ó jẹ́ ọrẹ ohun jíjẹ Àlùfáà yóò sun ẹbọ ìrántí lára ọkà àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa Ìjìyà Fún Ẹ̀ṣẹ̀ Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ará Ísírẹ́lì tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrin Ísírẹ́lì, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún mólékì, kí wọ́n pa á, kí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa Èmi tìkarami yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, ń ó sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ fún òrìṣà mólékì ó ti ba ibi mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú Bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá mójú kúrò lára irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún òrìṣà mólékì tí wọn kò sì pa irú ẹni bẹ́ẹ̀ Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ àti gbogbo ìdílé rẹ̀, èmi yóò sì ge wọn kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọn òun àti gbogbo àwọn tí ó dìjọ ṣe àgbérè tọ òrìṣà mólékì lẹ́yìn  Bí ẹnikẹ́ni bá tọ àwọn abókúsọ̀rọ̀ àti àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn lọ, tí ó sì ṣe àgbérè tọ̀ wọ́n lẹ́yìn Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ Èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀  Torí náà ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, torí pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín Ẹ máa kíyèsí àṣẹ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́ Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́  Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé bàbá tàbí ìyá rẹ̀ ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀ torí pé ó ti ṣépè lé bàbá àti ìyá rẹ̀  Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládúgbò rẹ̀ lòpọ̀ ọkùnrin àti obìnrin náà ni kí ẹ sọ ní òkúta pa  Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya bàbá rẹ̀ lòpọ̀ ti tàbùkù bàbá rẹ̀ Àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn  Bí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa, wọ́n ti ṣe ohun tí ó lòdì, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn  Bí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin mìíràn lòpọ̀ bí wọ́n í ti bá obìnrin lòpọ̀ àwọn méjèèjì ti ṣe ohun ìríra pípa ni kí ẹ pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn  Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ tìyatọmọ papọ̀ ìwà búburú ni èyí iná ni kí ẹ fi sun wọ́n, òun àti àwọn méjèèjì, kí ìwà búburú má baà gbilẹ̀ láàrin yín  Bí ọkùnrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, ẹ gbọdọ̀ pa ọkùnrin náà àti ẹranko náà  Bí obìnrin kan bá sún mọ́ ẹranko tí ó sì bá a lòpọ̀ obìnrin náà àti ẹranko náà ni kí ẹ pa ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì wà lórí ara wọn  Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ arábìnrin rẹ̀ yálà ọmọbìnrin bàbá rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀, ohun ìtìjú ni èyí Ẹ ó gé wọn kúrò lójú àwọn ènìyàn wọn ó ti tàbùkù arábìnrin rẹ̀ Ẹ̀bi rẹ̀ yóò wá sórí rẹ̀  Bí ọkùnrin kan bá sún mọ́ obìnrin, ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀ Ó ti tú orísun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ Òun náà sì gbà á láàyè Àwọn méjèèjì ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọn  Má ṣe bá arábìnrin bàbá tàbí ti ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí o ti tú ìhòòhò ìbátan rẹ Ẹ̀yin méjèèjì ni yóò ru ẹ̀bi yín  Bí ọkùnrin kan bá bá aya arákùnrin bàbá rẹ̀ lòpọ̀ ó ti tàbùkù arákùnrin bàbá rẹ̀ A ó jẹ wọ́n ní ìyà wọn yóò sì kú láìlọ́mọ  Bí ọkùnrin kan bá gba aya arákùnrin rẹ̀, ohun àìmọ́ ni èyí, ó ti tàbùkù arákùnrin rẹ̀, wọn ó wà láìlọ́mọ  Kí ẹ pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n Kí ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín láti máa gbé má baà pọ̀ yín jáde Ẹ má ṣe tẹ̀lé àṣà àwọn orílẹ̀ èdè tí mo lé jáde níwájú yín torí pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ń ṣe, tí mo kóríra wọn Ṣùgbọ́n mo ti sọ fún yín pé, Ẹ̀yin ni yóò jogún ilẹ̀ wọn Èmi yóò sì fi fún yín láti jogún ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn yòókù  Ẹ gbọdọ̀ pààlà sáàrin ẹran tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́ Láàrin ẹyẹ tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́ Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ àwọn ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí ohunkohun tí ń rìn lórí ilẹ̀ èyí tí mo yà sọ́tọ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun àìmọ́ Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé èmi Olúwa fẹ́ mímọ́ Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀ èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi  Ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó jẹ́ abókúsọ̀rọ̀ tàbí oṣó láàrin yín ni kí ẹ pa Ẹ sọ wọ́n ní òkúta, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn   Òfin Fún Àwọn Àlùfáà Olúwa sọ fún Mósè wí pe, Bá àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Árónì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé Ẹnikẹ́ni nínú wọn kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí àwọn ènìyàn wọn tí ó kù Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe àwọn tí ó sún mọ́ ọn bí ìyá rẹ̀, bàbá rẹ̀, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin, àti arákùnrin rẹ̀ Tàbí fún arábìnrin rẹ̀ tí kò ì tí ì wọ ilé ọkọ tí ó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ Nítorí tí arábìnrin bẹ́ẹ̀, ó lè sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ Nítorí tí ó jẹ́ olórí òun kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ ba ara rẹ̀ jẹ́ láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀  Àlùfáà kò gbọdọ̀ fá irun orí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ rẹ́ irungbọ̀n rẹ̀ Kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara rẹ̀ láti fi hàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀ Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n má baà sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di àìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń fí iná sun ẹbọ sí Olúwa wọn, ti ó jẹ oúnjẹ Ọlọ́run wọn Nítorí náà wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́  Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ aṣẹ́wó tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀ sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ máa kà wọ́n sí mímọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ oúnjẹ fún mi Èmi ni Olúwa , mo jẹ́ mímọ́, mo sì ya àwọn ènìyàn mi sí mímọ́  Bí ọmọbìnrin àlùfáà bá ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa sísọ ara rẹ̀ di aṣẹ́wó ó dójú ti bàbá rẹ̀, a ó sun ún ní iná  Lẹ́yìn tí a ti fi òróró yan olórí àlùfáà láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀ tí a sì ti fi amì òróró yàn láti máa wọ aṣọ àlùfáà, gbọdọ̀ tọ́jú irún orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀ Kí ó ma ṣe wọlé tọ òkú lọ, kí ó má ṣe sọ ará rẹ di àìmọ́ nítorí baba tàbí nítorí ìyá rẹ̀ Kò gbọdọ̀ kúrò ní ibi mímọ́ Ọlọ́run tàbí kí ó sọ ọ́ di aláìmọ́ torí pé a ti fi ìfòróróyàn Ọlọ́run yà á sí mímọ́ Èmi ni Olúwa  Ọmọbìnrin tí yóò fẹ́ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí kò mọ Ọkùnrin rí Kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀ sílẹ̀ tàbí obìnrin tí ó ti fi àgbérè ba ara rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ obìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí, láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ Kí ó má baà sọ di aláìmọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ Èmi ni Olúwa tí ó sọ ọ́ di mímọ́   Olúwa sì bá Mósè sọ̀rọ̀ pé, Sọ fún Árónì pé Ẹnikẹ́ni nínú ìran yín tí ó bá ní àrùn kan kò yẹ láti máa rú ẹbọ ohun jíjẹ́ fún mi Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ sún mọ́ ibi ẹbọ náà Kò gbọdọ̀ sí afọ́jú tàbí arọ, alábùkù ara tàbí àwọn tí ara wọn kò pé Kò gbọdọ̀ sí ẹnikẹ́ni yálà ó rọ lápá lẹ́sẹ̀, tàbí tí ó jẹ́ abuké, tàbí tí ó ya aràrá tàbí tí ó ní àìsàn ojú tàbí tí ó ní egbò tàbí tí a ti yọ nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ Kò gbọdọ̀ sí iran àlùfáà tí ó jẹ́ alábùkù ara tí ó gbọdọ̀ wá fi iná sun ẹbọ sí Ọlọ́run Nítorí pé ó jẹ́ alábùkù, kò gbọdọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé ẹbọ wá fún Olúwa Ó lè jẹ́ oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ tàbí èyí tí ó mọ́ jùlọ ṣùgbọ́n torí pé ó ní àbùkù kò gbọdọ̀ sún mọ́ ibi aṣọ títa tàbí pẹpẹ Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ba ibi mímọ́ mi jẹ́ torí pé, Èmi Olúwa ló ti sọ wọ́n di mímọ́   Wọ̀nyí ni àwọn ohun tí Mósè sọ fún Árónì, àwọn ọmọ Árónì àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì Àwọn Ọrẹ-Ẹbọ Tí Kò Jẹ́ Ìtẹ́wọ́gbà Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n fi ọ̀wọ̀ fún ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má baà ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ Èmi ni Olúwa Sọ fún wọn pé Fún àwọn ìran tí ń bọ̀ Bí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ yín tí kò mọ́ bá wá síbi ọrẹ mímọ́ tí àwọn ara Ísírẹ́lì ti yà sọ́tọ̀ fún Olúwa , kí ẹ yọ ẹni náà kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà ní iwájú mi Èmi ni Olúwa  Bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Árónì bá ní àrùn ara tí ń ran ni, tàbí ìtújáde nínú ara Ó lè má jẹ ọrẹ mímọ́ náà títí di ìgbà tí a ó fi wẹ̀ ẹ́ mọ́ Òun tún lè di aláìmọ́ bí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí òkú nǹkan bá sọ di àìmọ́ tàbí bí ó bá farakan ẹnikẹ́ni tí ó ní ìtújáde Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan èyíkéyìí nínú ohun tí ń rákò, tí ó sọ ọ́ di aláìmọ́, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó sọ ọ́ di àìmọ́, ohunkóhun yówù kí àìmọ́ náà jẹ́ Ẹni náà tí ó fọwọ́ kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ Kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyí nínú ọrẹ mímọ́ àyàfi bí ó bá wẹ ara rẹ̀ Bí òòrùn bá wọ̀, ẹni náà di mímọ́, lẹ́yìn náà ni ó tó le jẹ ọrẹ mímọ́, torí pé wọ́n jẹ́ oúnjẹ rẹ̀ Kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti kú sílẹ̀, tàbí tí ẹranko fàya, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́ Èmi ni Olúwa  Kí àwọn àlùfáà pa ìlànà mi mọ́, kí wọn má baà jẹ̀bi, kí wọn sì kú nítorí pé wọ́n ṣe ọrẹ wọ̀nyí pẹ̀lú fífojútẹ́ḿbẹ́lú wọn Èmi ni Olúwa tí ó sọ wọ́n di mímọ́  Kò sí ẹnikẹ́ni lẹ́yìn ìdílé àlùfáà tí ó le jẹ ọrẹ mímọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni, àlejò àlùfáà tàbí alágbàṣe rẹ̀ kò le jẹ ẹ́ Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá ra ẹrú, pẹ̀lú owó, tàbí tí a bí ẹrú kan nínú ìdílé rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ oúnjẹ rẹ̀ Bí ọmọbìnrin àlùfáà bá fẹ́ ẹni tí kì í ṣe àlùfáà, kò gbọdọ̀ jẹ nínú èyíkéyi nínú ohun ọrẹ mímọ́ Ṣùgbọ́n bí ọmọbìnrin àlùfáà bá jẹ́ opó tàbí tí a ti kọ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò lọ́mọ tí ó sì padà sínú ilé bàbá rẹ̀ láti máa gbé bẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀, ó le jẹ oúnjẹ bàbá rẹ̀ Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnikẹ́ni tí kò lẹtọ kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyí nínú oúnjẹ náà  Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì jẹ ọrẹ mímọ́ kan, ó gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe lórí ẹbọ náà fún àlùfáà, kí ó sì fi ìdámárùn ún ohun tí ọrẹ náà jẹ́ kún un Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wá ṣíwájú Olúwa di àìmọ́ Nípa fífi ààyè fún wọn láti jẹ ọrẹ mímọ́ náà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀bi tí wọn yóò san nǹkan fún wá sórí wọn Èmi ni Olúwa , tí ó sọ wọ́n di mímọ́   Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún Árónì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti fún gbogbo Ísírẹ́lì kí o sì wí fún wọn pé Bí ẹnikẹ́ni nínú yín yálà ọmọ Ísirẹ́lì ni tàbí àlejò tí ń gbé ní Ísírẹ́lì bá mú ẹ̀bùn wá fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa , yálà láti san ẹ̀jẹ́ tàbí ọrẹ àtinúwá Ẹ gbọdọ̀ mú akọ láìní àbùkù láti ara màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́, kí ó baà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín Ẹ má ṣe mú ohunkóhun tí ó ní àbùkù wá, torí pé kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín Bí ẹnikẹ́ni bá mú ọrẹ àlàáfíà wá láti inú agbo màlúù tàbí ti àgùntàn, fún Olúwa láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí fún ọrẹ àtinúwá Ó gbọdọ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láìní àbùkù Ẹ má ṣe fi ẹranko tí ó fọ́jú, tí ó farapa, tí ó yarọ, tí ó ní koko, tí ó ní èkúkú, èépá àti egbò kíkẹ̀ rúbọ sí Olúwa Ẹ kò gbọdọ̀ gbé èyíkeyi nínú wọn sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bi ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa Ẹ le mú màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù tàbí tí ó yọ iké wá fún ọrẹ àtinúwá ṣùgbọ́n kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ ẹ̀jẹ́ Ẹ má ṣe fi ẹranko tí kóró ẹpọ̀n rẹ̀ fọ́ tàbí tí a tẹ̀, tàbí tí a yà tàbí tí a là rúbọ sí Olúwa Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí ní ilẹ̀ yín Ẹ kò gbọdọ̀ gba irú ẹranko bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò kankan láti fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ sí Ọlọ́run yín A kò ní gbà wọ́n fún yín nítorí pé wọ́n ní àbùkù wọ́n sì díbàjẹ́   Olúwa sọ fún Mósè pé, Nígbà tí màlúù bá bímọ, tí àgùntàn bímọ, tí ewúrẹ́ sì bímọ, ọmọ náà gbọdọ̀ wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ fún ọjọ́ méje Láti ọjọ́ kèjọ ni ó ti di ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ àfinásun sí Olúwa Ẹ má ṣe pa màlúù àti ọmọ rẹ̀ tàbí àgùntàn àti ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ ọpẹ́ sí Olúwa , ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóò fí jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín Ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà gan an Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀ Èmi ni Olúwa Ẹ pa òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n Èmi ni Olúwa Ẹ má ṣe ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọdọ̀ mọ̀ mí ní mímọ́ Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́ Tí ó sì mú yín jáde láti Éjíbítì wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín Èmi ni Olúwa Ọdún Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Olúwa sọ fún Mósè wí pé, Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé, Ìwọ̀nyí ni àwọn àjọ̀dún tí mo ti yàn, àwọn àjọ̀dún ti Olúwa èyí tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí ìpàdé àjọ mímọ́  Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ le fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Ọjọ́ ìpàdé àjọ mímọ́ Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé Ọjọ́ ìsinmi Olúwa ni  Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọdún tí Olúwa yàn, ìpàdé àjọ mímọ́ tí ẹ gbọdọ̀ kéde lákókò wọn Àjọ ìrékọjá Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní Ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kìnm-ín-ní ni àjọ̀dún àkàrà àìwú tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ fún ọjọ́ méje ni ẹ gbọdọ̀ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà Ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́ yín Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa Ní ọjọ́ keje, ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́   Olúwa sọ fún Mósè pe Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé, Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fún yín, tí ẹ bá ń ṣe ìkórè, kí ẹ mú síírì ọkà àkọ́kọ́ tí ẹ kórè wá fún àlùfáà Kí o fí síírì ọkà náà níwájú Olúwa , kí ó le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín kí àlùfáà fì í ní ọjọ́ kejì ìsinmi Ní ọjọ́ tí ẹ bá fí síírì ọkà náà, kí ẹ mú ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dúnkan láìní àbùkù rú ẹbọ sísun sí Olúwa Pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ tí ó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ẹ́fà ti ìyẹ̀fun, tí a fi òróró pò ọrẹ tí a fi iná ṣe fún Olúwa òórùn dídùn pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀ tí í ṣe ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hini Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé  Ẹ ka ọ̀sẹ̀ méje gbangba, láti ọjọ́ kejì ọjọ́ ìsinmi, àní ọjọ́ tí ẹ mú sììrì ọkà fífì wá Ẹ ka àádọ́ta ọjọ́ títí dé ọjọ́ kejì ọ̀sẹ̀ méjèèje, kí ẹ sì mú ọrẹ ọkà titun wá fún Olúwa Láti ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, ẹ mú ìṣù àkàrà méjì tí a fi òṣùwọ̀n ìdáméjì nínú mẹ́wàá tí ẹ́fà ti ìyẹ̀fun, tí a fi ìwúkàrà ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì àkọ́so sí Olúwa Ẹ fi akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù, ọmọ màlúù kan àti àgbò méjì kún àkàrà yìí wọn yóò jẹ́ ọrẹ sísun sí Olúwa Lẹ́yìn náà kí ẹ fi akọ ewúrẹ́ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọ̀dọ́ àgùntàn méjì ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan fún ọrẹ àlàáfíà Kí àlùfáà fí ọ̀dọ́ àgùntàn méjèèjì náà níwájú Olúwa bí i ọrẹ fífì pẹ̀lú oúnjẹ àkọ́so wọn jẹ́ ọrẹ mímọ́ sí Olúwa fún àlùfáà Ní ọjọ́ yìí náà ni kí ẹ kéde ìpàdé àjọ mímọ́ ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́ Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀ níbi yòówù tí ẹ ń gbé  Nígbà tí ẹ bá kórè ilẹ̀ yín ẹ má ṣe kórè dé ìkangun oko yín, tàbí kí ẹ padà gé èyí tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ nínú ìkórè yín Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn tálákà àti àwọn àlejò Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín   Olúwa sọ fún Mósè pé Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, kí ẹ ní ọjọ́ ìsinmi, ìpàdé àjọ mímọ́ tí a fi fèrè fífọn ṣe ìrántí Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojúmọ́, ṣùgbọ́n ẹ mú ọrẹ tí a fi iná sun wá ṣíwájú Olúwa   Olúwa sọ fún Mósè pé, Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni ọjọ́ ètùtù Ẹ ni ìpàdé àjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣẹ́ ara yín kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, torí pé ọjọ́ ètùtù ni, nínú èyí tí a ń ṣe ètùtù fún yín níwájú Olúwa Ọlọ́run yín Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣẹ́ ara rẹ̀ ní ọjọ́ náà ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ Èmi yóò pa ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́kiṣẹ́ ní ọjọ́ náà run kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé Ọjọ́ ìsinmi ni fún yín, ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà, títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, ni kí ẹ fi sinmi Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé Ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù keje ni kí àjọ̀dún ọdún Àgọ́ ti Olúwa bẹ̀rẹ̀ kí ó sì wà títí di ọjọ́ méje Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìpàdé mímọ́ ṣẹ kò gbọdọ̀ e iṣẹ́ ojúmọ́ Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá, ní ọjọ́ kẹjọ ẹ pe ìpàdé mímọ́ kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa , èyí jẹ́ ìpàdé tí ó gbẹ̀yìn ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojojúmọ́  Torí náà, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹẹ̀dógún osù kéje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti kórè ilẹ̀ náà, ẹ se àjọ̀dún yìí fún Olúwa ní ọjọ́ méje Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹjọ pẹ̀lú si tún jẹ́ ọjọ́ ìsinmi Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí ẹ mú àṣàyàn èso láti orí igi, igi tẹ́ẹ́rẹ́ etídò, àti ẹ̀ka igi tó rúwé, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje Ẹ ṣe èyí ní àjọ̀dún sí Olúwa fún ọjọ́ méje lọ́dọọdún Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀ Ẹ ṣe é ní oṣù keje Ẹ gbé inú àgọ́ fún ọjọ́ méje Kí gbogbo ọmọbíbí Ísírẹ́lì gbé nínú àgọ́ Kí àwọn ìran yín le mọ̀ pé mo mú kí Ísírẹ́lì gbé nínú àgọ́, nígbà tí mo mú wọn jáde ní Éjíbítì Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín   Báyìí ni Mósè kéde àwọn àṣàyàn ọdún Olúwa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Tẹ́ Òróró Òun Àkàrà Ṣíwájú Olúwa sọ fún Mósè pé Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti mú òróró tí ó mọ́ tí a fún láti ara ólífì wá láti fi tan iná, kí àtùpà lè máa jò láì kú Lẹ́yìn aṣọ títa tibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Árónì ti tan iná náà níwájú Olúwa , láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójojúmọ́ Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀ Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá àtùpà tí a fi wúrà ṣe níwájú Olúwa ni kí ó máa jó lójojúmọ́ Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdáméjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ẹfà fún ìṣù kọ̀ọ̀kan Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fàmẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó gòólù bọ̀ Èyí tí ó wà níwájú Olúwa Ẹ fi ojúlówó tùràrí sí ọnà kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìpín ìrántí láti dípò àkàrà, àti láti jẹ ẹbọ ọrẹ iná sísun fún Olúwa Búrẹ́dì yìí ni kí ẹ gbé wá ṣíwájú Olúwa nígbàkugbà, lọ́sẹ̀ọ̀sẹ̀, nítorí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú ayérayé Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ló ni ín Wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ torí pé ó jẹ́ ipa tí ó mọ́ jùlọ ti ìpín wọn ojojúmọ́ nínú ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa Ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì baba rẹ̀ sì jẹ́ ará Éjíbítì Ó jáde lọ láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìjà sì ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ láàrin òun àti ọmọ Ísírẹ́lì kan Ọmọkùnrin arábìnrin Ísírẹ́lì náà sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Olúwa pẹ̀lú èpè Wọ́n sì mú-un tọ Mósè wá Wọ́n fi í sínú àtìmọ́lé kí Olúwa to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn Olúwa sì sọ fún Mósè pé Mú asọ̀rọ̀òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fi hàn pé ó jẹ̀bi Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé Bí ẹnikẹ́ni bá ṣépè lé Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀òdì sí orúkọ Olúwa ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọbíbí Ísírẹ́lì, bí ó bá ti sọ̀rọ̀òdì sí orúkọ Olúwa , pípa ni kí ẹ pa á  Ẹni tí ó bá gba ẹmi ènìyàn pípa ni kí ẹ pa á Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn ẹlòmíràn, kí ó dá a padà—ẹ̀mí dípò ẹ̀mí Bí ẹnìkan bá pa ẹnìkejì rẹ̀ lára ohunkóhun tí ó ṣe ni kí ẹ ṣe sí i Bí ó bá ṣẹ́ egungun ẹnìkan, egungun tirẹ̀ náà ni kí a ṣẹ́, bí ó bá fọ́ ojú ẹnìkan, ojú tirẹ̀ náà ni kí a fọ́, bí ó bá ká eyín ẹnìkan, eyín tirẹ̀ náà ni kí a ká Bí ó ti pa ẹnìkejì lára náà ni kí ẹ pa òun náà lára Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹran ọ̀sìn gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ni kí ẹ pa Òfin kan náà ló wà fún àlejò àti fún ọmọ Ísírẹ́lì Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín   Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì mú asọ̀rọ̀òdì náà lọ sí ẹ̀yìn àgọ́ wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mósè Ọdún Ìsinmi Olúwa sọ fún Mósè ní orí òkè Sínáì pé, Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín ilẹ̀ náà gbọdọ̀ sinmi fún Olúwa Ọdún mẹ́fà ni kí ẹ fi gbin èso ọgbà yín, kí ẹ sì kórè èso wọn Ṣùgbọ́n ní ọdún keje kí ilẹ̀ náà ní ìsinmi ìsinmi fún Olúwa Ẹ má ṣe gbin èso ọgbà yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ rò wọ́n Ẹ má ṣe kórè ohun tí ó tìkálárarẹ̀ hù ẹ má ṣe kórè èso àjàrà ọgbà tí ẹ ò tọ́jú Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ ní ìsinmi fún ọdún kan Ohunkóhun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde ní ọdún ìsinmi ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún yín àní fún ẹ̀yin tìkálárayín, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín, àwọn alágbàṣe àti àwọn tí ń gbé pẹ̀lú yín fún ìgbàdíẹ̀ Fún àwọn ohun ọ̀sìn yín, àti àwọn ẹranko búburú ní ilẹ̀ yín Ohunkóhun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde ní ẹ lè jẹ  Ọdún ìsinmi méje èyí tí í ṣe ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta ni kí ẹ kà Lẹ́yìn náà, kí ẹ fọn fèrè ní gbogbo ibikíbi ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kéje ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ Ní ọjọ́ ètùtù yìí, ẹ fọn fèrè yíká gbogbo ilẹ̀ yín Ẹ ya àádọ́ta ọdún náà sọ́tọ̀ kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo ẹni tí ń gbé ilẹ̀ náà Yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín Kí olúkúlùkù padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀ Àádọ́ta ọdún ni yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín Ẹ má ṣe gbin ohunkóhun, ẹ kò sì gbọdọ̀ kórè ohun tí ó hù fúnrarẹ̀ tàbí kí ẹ kórè ọgbà àjàrà tí ẹ kò dá Torí pé ọdún ìdásílẹ̀ ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún yín Ẹ jẹ ohun tí ẹ mú jáde nínú oko náà  Ní ọdún idásílẹ̀ yìí, kí olúkúlùkù gbà ohun ìní rẹ̀ padà  Bí ẹ bá ta ilẹ̀ fún ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín tàbí bí ẹ bá ra èyíkéyí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ Kí ẹ ra ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yín ní gẹ́gẹ́ bí iye owó tí ó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ pé, kí òun náà sì ta ilẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí iye ọdún rẹ̀ tó kù láti kórè Bí iye ọdún rẹ̀ bá gùn, kí iye owó rẹ̀ pọ̀, bí iye ọdún rẹ̀ bá kúrú, kí iye owó rẹ̀ kéré, torí pé ohun tí ó tà gan an ní iye èso rẹ̀ Ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ, ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín  Ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà mi, kí ẹ sì kíyèsí láti pa òfin mi mọ́, kí ẹ baà le máa gbé láìléwu ní ilẹ̀ náà Nígbà yìí ni ilẹ̀ náà yóò so èso rẹ̀, ẹ ó sì jẹ àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé láìléwu Ẹ le bèèrè pé, Kí ni àwa ó jẹ ní ọdún keje, bí a kò bá gbin èso tí a kò sì kórè Èmi ó pèsè ìbùkún sórí yín tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ yín yóò so èso tó tó fún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn rẹ̀ Bí ẹ bá gbin èso yín ní ọdún kejọ, àwọn èso ti tẹ́lẹ̀ ní ẹ ó máa jẹ, títí tí ìkórè ti ọdún kẹsàn-án yóò fi dé  Ẹ má ṣe ta ilẹ̀ yín ní àtàpa torí pé ẹ̀yin kọ́ lẹ ni-ín, ti Ọlọ́run ni, ẹ̀yin jẹ́ àlejò àti ayálégbé, Ní gbogbo orílẹ̀ èdè ìní yín, ẹ fi àyè sílẹ̀ fún ìràpadà ilẹ̀ náà  Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín bá talákà, débi pé ó ta ara àwọn ẹrù rẹ̀, kí ará ilé rẹ̀ tí ó sún mọ́ ọ ra ohun tí ó tà padà Ẹni tí kò ní ẹni tó lè ràápadà fún un, tí òun fúnrarẹ̀ sì ti lọ́rọ̀, tí ó sì ní ànító láti rà á Kí ó mọ iye owó tí ó jẹ fún iye ọdún tí ó tà á, kí ó dá iye tí ó kù padà fún ẹni tí ó tà á fún lẹ́yìn náà, ó lè padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ Ṣùgbọ́n bí kò bá rí ọ̀nà àti san án padà fún un Ohun tí ó tà wà ní ìkáwọ́ ẹni tí ó ràá títí di ọdún ìdásílẹ̀ Kí ó dáa padà fún ẹni tí ó ni i ní ọdún ìdásílẹ̀, ẹni tí ó ni í tẹ́lẹ̀ lè tún padà gbà ohun ìní rẹ̀  Bí arákùnrin kan bá ta ilẹ̀ tí ó wà nínú ìlú, ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á padà láàrin ọdún kan sí àkókò tí ó tà á Ṣùgbọ́n bí kò bá rà á padà láàrin ọdún náà ilé náà tí ó wà láàrin ìlú ni kí ó yọ̀ǹda pátapáta fún ẹni tí ó rà á, àti àwọn ìdílé rẹ̀ Kí wọ́n má da padà ní ọdún ìdásílẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn ilé tí ó wà ní abúlé láìní odi ni kí a kà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ oko, a lè rà wọ́n padà, kí wọ́n sì da padà ní ọdún ìdásílẹ̀  Àwọn ọmọ Léfì ní ẹ̀tọ́, nígbàkugbà láti ra ilẹ̀ wọn, tí ó jẹ́ ohun ìní wọn ní àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Léfì Torí náà ohun ìní àwọn ọmọ Léfì ni wọ́n rà padà, fún àpẹẹrẹ, èyí ni pé ilẹ̀ tí a bá tà ní ìlúkílú tí ó jẹ́ tiwọn, ó sì gbọdọ̀ di dídápadà ní ọdún ìdásílẹ̀, torí pé àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní ìlú àwọn Léfì ni ìní wọn láàrin àwọn ará Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí wọ́n ti ń da ẹran tí ó jẹ́ ti ìlú wọn, wọn kò gbọdọ̀ tà wọ́n, ilẹ̀ ìní wọn láéláé ni  Bí arákùnrin yín kan bá talákà tí kò sì le è pèsè fún àìní ara rẹ̀ ẹ pèsè fún un bí ẹ ti ń ṣe fún àwọn àlejò tàbí àwọn tí ẹ gbà sílé kí ó baà leè máa gbé láàrin yín Ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé kankan lọ́wọ́ rẹ̀ ẹ bẹ̀rù Olúwa kí arákùnrin yín leè máa gbé láàrin yín Ẹ má ṣe gba èlé lórí owó tí ẹ yá a bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ èrè lórí oúnjẹ tí ẹ tà fún un Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì láti fún yín ní ilẹ̀ Kénánì àti láti jẹ́ Ọlọ́run yín  Bí arákùnrin yín kan bá talákà débi pé ó ta ara rẹ̀ fún ọ bí ẹrú Má se lò ó bí ẹrú Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tàbí àlejò láàrin yín kí ó máa ṣiṣẹ́ sìn ọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀ Nígbà náà ni kí ó yọ̀ǹda òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n padà sí ìdílé wọn àti sí ilẹ̀ ìní bàbá wọn Torí pé ìránṣẹ́ mi ni àwọn ará Ísírẹ́lì jẹ́ Ẹni tí mo mú jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, torí èyí ẹ kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú Ẹ má ṣe rorò mọ́ wọn ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín  Àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín lè jẹ́ láti orílẹ̀ èdè tí ó yí yín ká Ẹ lè ra àwọn ẹrú wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn Bákan náà, ẹ sì le è ra àwọn àlejò tí ń gbé láàrin yín, àti àwọn ìdílé wọn tí a bí sáàrin yín Wọn yóò sì di ohun ìní yín Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ bí ogún fún àwọn ọmọ yín Wọ́n sìle sọ wọ́n di ẹrú títí láé Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rorò mọ́ ọmọ Ísírẹ́lì kankan  Bí àlejò kan láàrin yín tàbí ẹni tí ń gbé àárin yín fún ìgbà díẹ̀ bá lọ́rọ̀ tí ọmọ Ísírẹ́lì sì talákà débi pé ó ta ara rẹ̀ lẹ́rú fún àlejò tàbí ìdílé àlejò náà Ó lẹ́tọ́ si ki a rà á padà lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ta ara rẹ̀ Ọ̀kan nínú ìbátan rẹ̀ le è rà á padà Àbúrò bàbá rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá a tan nínú ìdílé rẹ̀ le è rà á padà Bí ó bá sì ti là ó lè ra ara rẹ̀ padà Kí òun àti olówó rẹ̀ ka iye ọdún tí ó ta ara rẹ̀ títí dé ọdún ìdásílẹ̀ kí iye owó ìdásílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ iye tí wọ́n ń san lórí alágbàṣe fún iye ọdún náà Bí iye ọdún rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù bá pọ̀, kí iye owó fún ìràpadà rẹ̀ pọ̀ Bí ọdún rẹ̀ kò bá pọ̀ sí àkókò ìdásílẹ̀, kí ó ṣe ìṣírò rẹ̀, kí ó sì san owó náà bí iye ìṣírò rẹ̀ Bí ẹ ti ń ṣe sí i lọ́dọọdún, ẹ rí i dájú pé olówó rẹ̀ kò korò mọ́ ọ  Bí a kò bá rà á padà nínú gbogbo ọ̀nà wọ̀nyí, kí ẹ tú òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀ Torí pé ìránṣẹ́ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ fún mi Ìránṣẹ́ mi ni wọ́n, tí mo mú jáde láti Éjíbítì wá Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín Èrè Ìgbọràn Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mọ ère òrìsà, tàbí kí ẹ̀yin gbe ère kalẹ̀ tàbí kí ẹ̀yin gbẹ́ ère òkúta kí ẹ̀yin má sì gbẹ́ òkúta tí ẹ̀yin yóò gbé kalẹ̀ láti sìn Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín  Ẹ pa ọjọ ìsinmi mi mọ́ kí ẹ̀yin sì bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi Èmi ni Olúwa  Bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ẹ̀yin sì sọ́ra láti pa òfin mi mọ́ Èmi yóò rọ̀jò fún yín ní àkókò rẹ̀, kí ilẹ̀ yín le mú èso rẹ̀ jáde bí ó tí yẹ kí àwọn igi eléso yín so èso Èrè oko yín yóò pọ̀ débí pé ẹ ó máa pa ọkà títí di àsìkò ìkórè igi eléso, ẹ̀yin yóò sì máa gbé ní ilé yín láì léwu  Èmi yóò fún yín ní àlàáfíà ní ilẹ̀ yín, ẹ̀yin yóò sì sùn láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni Èmi yóò mú kí gbogbo ẹranko búburú kúrò ní ilẹ̀ náà bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì sí ogun mọ́ Ẹ̀yin yóò lé àwọn ọ̀ta yín wọn yóò sì tipa idà kú Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa sẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn Àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa sẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá Àwọn ọ̀ta yín yóò tipa idà kú níwájú yín  Èmi yóò fi ojú rere wò yín Èmi yóò mú kí ẹ bí sí i, èmi yóò jẹ́ kí ẹ pọ̀ sí i Èmi yóò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú yín Àwọn èrè oko yín yóò pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa jẹ èrè ọdún tí ó kọjá, ẹ̀yin ó sì kó wọn jáde kí ẹ̀yin lè rí àyè kó túntún sí Èmi yóò kọ́ àgọ́ mímọ́ mi sí àárin yín Èmi kò sì ní kórìíra yín Èmi yóò wà pẹ̀lú yín Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì kí ẹ̀yin má baà jẹ́ ẹrú fún wọn mọ́ Mo sì já ìdè yín mo sì mú kí ẹ̀yin máa rìn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a gbé lórí sókè  Bí ẹ̀yin kò bá fetí sí mi tí ẹ̀yin kò sì ṣe gbogbo òfin wọ̀nyí Bí ẹ̀yin bá kọ àṣẹ mi tí ẹ̀yin sì kórira òfin mi, tí ẹ̀yin sì kùnà láti pa ìlànà mi mọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ sí májẹ̀mú mi Èmi yóò se àwọn nǹkan wọ̀nyí sí yín Èmi yóò mú ìpáyà òjijì bá yín àwọn àrùn afinisòfò, àti ibà afọ́nilójú, tí í pani díẹ̀díẹ̀ Ẹ̀yin yóò gbin èso ilẹ̀ yín lásán nítorí pé àwọn ọ̀ta yín ni yóò jẹ gbogbo ohun tí ẹ̀yin ti gbìn Èmi yóò dojú kọ yín títí tí ẹ̀yin ó fi di ẹni ìkọlù àwọn tí ó kóríra yín ni yóò sì ṣe àkóso lórí yín Ìbẹ̀rù yóò mú yín débi pé ẹ̀yin yóò máa sá kákìkiri nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé yín  Bí ẹ̀yin kò bá wá gbọ́ tèmi lẹ́yìn gbogbo èyí Èmi yóò fi kún ìyà yín ní ìlọ́po méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín Èmi yóò fọ́ agbára ìgbéraga yín ojú ọ̀run yóò le koko bí irin ilẹ̀ yóò sì le bí idẹ Ẹ ó máa lo agbára yín lásán torí pé ilẹ̀ yín kì yóò so èso, bẹ́ẹ̀ ni àwọn igi yín kì yóò so èso pẹ̀lú  Bí ẹ bá tẹ̀ṣíwájú láì gbọ́ tèmi, Èmi yóò tún fa ìjayà yín le ní ìgbà méje gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín Èmi yóò rán àwọn ẹranko búburú sí àárin yín, wọn yóò sì pa àwọn ọmọ yín, wọn yóò run agbo ẹran yín, díẹ̀ nínú yín ni wọn yóò ṣẹ́kù kí àwọn ọ̀nà yín lè di ahoro  Bí ẹ kò bá tún yípadà lẹ́yìn gbogbo ìjìyà wọ̀nyí, tí ẹ sì tẹ̀síwájú láti lòdì sí mi Èmi náà yóò lòdì sí yín Èmi yóò tún fa ìjìyà yín le ní ìlọ́po méje ju ti ìṣáájú Èmi yóò mú ogun wá bá yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín láti fi gbẹ̀san májẹ̀mú mi tí ẹ kò pa mọ́ Bí ẹ ba sálọ sí ìlú yín fún ààbò Èmi yóò rán àjàkálẹ̀-àrùn sí ààrín in yín Àwọn ọ̀ta yín, yóò sì ṣẹ́gun yín Èmi yóò dá ìpèsè oúnjẹ yín dúró, débi pé inú àrò kan ni obìnrin mẹ́wàá yóò ti máa ṣe oúnjẹ yín Òṣùwọ̀n ni wọn yóò fi máa yọ oúnjẹ yín Ẹ ó jẹ ṣùgbọ́n, ẹ kò ní yó  Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ kò bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì lòdì sí mi, Ní ìbínú mi èmi yóò korò sí yín, èmi tìkara mi yóò fìyà jẹ yín ní ìgbà méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín Ebi náà yóò pa yín débi pé ẹ ó máa jẹ ẹran ara àwọn ọmọ yín ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yín obìnrin Èmi yóò wó àwọn pẹpẹ òrìṣà yín, lórí òkè níbi tí ẹ ti ń sìn Èmi yóò sì kó òkú yín jọ, sórí àwọn òkú òrìṣà yín Èmi ó sì kóríra yín Èmi yóò sọ àwọn ìlú yín di ahoro, èmi yóò sì ba àwọn ilé mímọ́ yín jẹ́ Inú mi kì yóò sì dùn sí òórùn ọrẹ yín mọ́ Èmi yóò pa ilẹ̀ yín run débi pé ẹnu yóò ya àwọn ọ̀ta yín tí ó bá gbé ilẹ̀ náà Èmi yóò mú ogun dé bá yín Èmi yóò sì fọ́n yín ká gbogbo àwọn ilẹ̀ àjèjì, ilẹ̀ yín yóò sì di ahoro àwọn ìlú yín ni a ó sì parun Ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi fún gbogbo ìgbà tí ẹ fi wà ní ilẹ̀ àjèjì tí ẹ kò fi lò ó Ìlẹ̀ náà yóò sinmi láti fi dípò ọdún tí ẹ kọ̀ láti fún un Níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò lò ó, ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi tí kò ní lákòókò ìsinmi rẹ̀ lákókò tí ẹ fi ń gbé orí rẹ̀  Èmi yóò jẹ́ kí ó burú fún àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ ìgbékùn débi pé ìró ewé tí ń mì lásán yóò máa lé wọn sá Ẹ ó máa sáré bí ìgbà tí wọ́n ń lé yín lójú ogun Ẹ ó sì subú láìsí ọ̀ta láyìíká yín Wọn yóò máa subú lu ara wọn, bí ẹni tí ń sá fún ogun nígbà tí kò sí ẹni tí ń lé yín Ẹ̀yin kì yóò sì ní agbára láti dúró níwájú ọ̀ta yín Ẹ̀yin yóò ṣègbé láàrin àwọn orílẹ̀ èdè abọ̀rìṣà Ilẹ̀ ọ̀ta yín yóò sì jẹ yín run Àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú yín ni yóò sòfò dànù ní ilẹ̀ ọ̀ta yín torí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ti àwọn babańlá yín  Bí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ti babańlá wọn, ìwà ìṣọ̀tẹ̀ wọn àti bí wọ́n ti ṣe lòdì sí mi Èyí tó mú mi lòdì sí wọn tí mo fi kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ọ̀ta wọn Nígbà tí wọ́n bá rẹ àìkọlà àyà wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá sì gba ìbáwí ẹ̀ṣẹ̀ wọn Nígbà náà ni Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Jákọ́bù àti pẹ̀lú Ísáákì àti pẹ̀lú Ábúráhámù Èmi yóò sì rántí ilẹ̀ náà Àwọn ènìyàn náà yóò sì fi ilẹ̀ náà sílẹ̀, yóò sì ní ìsinmi rẹ̀ nígbà tí ó bá wà lófò láìsí wọn níbẹ̀ Wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé wọ́n kọ àwọn òfin mi Wọ́n sì kórira àwọn àṣẹ mi Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n bá wà nílé àwọn ọ̀ta wọn, èmi kì yóò ta wọ́n nù, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kóríra wọn pátapáta èyi tí ó lè mú mi dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn Èmi ni Ọlọ́run wọn Nítorí wọn, èmi ó rántí májẹ̀mú mi tí mo ti ṣe pẹ̀lú babańlá wọn Àwọn tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì lójú gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè láti jẹ́ Ọlọ́run wọn Èmi ni Olúwa   Ìwọ̀nyí ni òfin àti ìlànà tí Olúwa fún Mósè ní orí òkè Sínáì láàrin òun àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ìràpadà Ohun Tí Ó Jẹ́ Ti Olúwa sọ fún Móse pé Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Bí ẹnìkan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì láti ya ènìyàn kan sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run nípa sísan iye tí ó tó, kí iye owó ọkùnrin láti ọmọ ogún ọdún sí ọgọ́ta ọdún jẹ́ àádọ́ta òṣùnwọ̀n Ṣékélì fàdákà, gẹ́gẹ́ bí oṣùwọ̀n sékélì ti ibi mímọ́ Olúwa Bí ẹni náà bá jẹ obìnrin, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n òṣùwọ̀n sékéli Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún sí ogún ọdún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ogún ṣékélì fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọdún márùn-ún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà márùn-ún fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà mẹ́ta fún obìnrin Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọgọ́ta ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́ẹ̀dógún fún ọkunrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ bá tálákà púpọ̀ débi pé kò lè san iye owó náà, kí a mú ẹni náà wá ṣíwájú àlùfáà, àlùfáà yóò sì dá iye owó tí ó lè san lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni náà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́  Bí ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ bá jẹ́ ẹranko èyí tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ̀gbà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún Olúwa , irú ẹran bẹ́ẹ̀ tí a bá fi fún Olúwa di mímọ́ Ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà kò gbọdọ̀ pàrọ̀ ẹran mìíràn, yálà kí ó pàrọ̀ èyí tí ó dára sí èyí tí kò dára tàbí èyí tí kò dára sí èyí tí ó dára Bí ó bá se bẹ́ẹ́ ti Olúwa ni ẹranko méjèèjì Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ níti ẹranko àìmọ́ tí a fi tọrẹ èyí tí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà bí i ọrẹ fún Olúwa Kí ọkùnrin náà mú ọrẹ náà lọ fún àlùfáà Kí àlùfáà díye lé e, gẹ́gẹ́ bí ó ti dára tàbí bí ó ti bàjẹ́ sí Iye owó náà ni kí ó jẹ́ Bí ẹni náà bá fẹ́ rà á padà ó gbọdọ̀ san iye owó rẹ̀ àti ìdá ogún iye owó náà láfikún  Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa kí àlùfáà kó sọ iye tí yóò san gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ náà ti dára tàbí bàjẹ́ sí iye owó náà ni kí ó jẹ́ Bí ẹni tí ó yá ilé náà sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà Jẹ́ kí ó fi ìdámárùn ún owó ìdíyelé rẹ̀ kún ún, yóò si jẹ́ tirẹ̀  Bí ẹnìkan bá sì ya ara ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa Iye tí ó bá jẹ́ ni kí wọ́n sètò gẹ́gẹ́ bí iye èso tí a ó fi gbìn ín Àádọ́ta ṣékélì fàdákà fún òṣùwọ̀n ómà èso bárílì Bí ó ba ṣe pé ní ọdún ìdásílẹ̀ ni ó yà ilẹ̀ náà sí mímọ́ Iye owó tí wọn sọ tẹ́lẹ̀ náà ni kí o san Bí ó bá ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ lẹ́yìn ọdún ìdásílẹ̀ kí àlùfáà sọ iye owó tí yóò san fún ọdún tó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ mìíràn tó pé iye owó tí ó gbọdọ̀ jẹ yóò dínkù Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà kí ó san iye owó náà pẹ̀lú àfikún ìdá márùn-ún Ilẹ̀ náà yóò sì di tirẹ̀ Bí kò bá ra ilẹ̀ náà padà tàbí bí ó bá tàá fún ẹlòmíràn kò le è ri rà padà mọ́ Bí a bá fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀ yóò di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí a fi fún Olúwa Yóò sì di ohun ìní àlùfáà  Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ tí ó ti rà tí kì í ṣe ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa Kí àlùfáà sọ iye tí ó tọ títí di ọdún ìdásílẹ̀ Kí ọkùnrin náà sì san iye owó náà ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ sí Olúwa Ní ọdún ìdásílẹ̀ ilẹ̀ náà yóò padà di ti ẹni tí ó ni ín, lọ́wọ́ ẹni tí a ti rà á Gbogbo iye owó wọ̀nyí gbọdọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ṣékélì ibi mímọ́  Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ ya gbogbo àkọ́bí ẹran sí mímọ́ Èyí jẹ́ ti Olúwa nípaṣẹ̀ òfin àkọ́bí yálà kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni tàbí àgùntàn, ti Olúwa ni Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹran tí kò mọ́, nígbà náà ni kí ó rà á padà gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, tàbí bí a kò bá rà á padà kí ẹ tà á gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀  Ohun tí a bá yà sí mímọ́ pátapáta láti ọwọ́ ẹnikẹ́ni sí Olúwa tàbí ẹranko tàbí ilẹ̀ tí ó jogún òun kò gbọdọ̀ tàá kí ó rà á padà Gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ bẹ́ẹ̀ di mímọ́ jùlọ fún Olúwa  Ẹni tí ẹ bá ti yà sọ́tọ̀ fún pípa, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ràá padà, pípa ni kí ẹ paá  Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà yálà tí èso ilẹ̀ ni, tàbí tí èso igi, ti Olúwa ni Mímọ́ ni fún Olúwa Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá nǹkan rẹ̀ padà o gbọdọ̀ fi márùn-ún kún un Gbogbo ìdámẹ́wàá àgbò àti ẹran ọ̀sìn, àní ìdámẹ́wàá ẹran tó bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran kí ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa Ènìyàn kò gbọdọ̀ wádìí bóyá ó dára tàbí kò dára, kò sì gbọdọ̀ pààrọ̀ rẹ̀ Bí ó bá pààrọ̀ rẹ̀ àti èyí tí ó pààrọ̀ àti èyí tí ó fi pààrọ̀ ni kí ó jẹ́ mímọ́ Wọn kò gbọdọ̀ rà á padà   Àwọn àṣẹ wọ̀nyí ni Olúwa pa fún Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní orí òkè Sínáì Ọrẹ Àlàáfíà  Bí ọrẹ ẹnìkan bá jẹ́ ọrẹ àlàáfíà, tí ó sì mú ẹran wá láti inú agbo màlúù yálà akọ tàbí abo, kí ó mú èyí tí kò ní àbùkù wá ṣíwájú Olúwa Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ Nígbà náà ni àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká Láti ara ọrẹ àlàáfíà ni kí ẹni náà ti mú ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa , gbogbo ọ̀nà tí ó bo nǹkan inú ẹran náà àti gbogbo ọ̀rá tí ó so mọ́ wọn Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti gbogbo ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín Nígbà náà ni àwọn ọmọ Árónì yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa  Bí ó bá ṣe inú agbo ewúrẹ́ àti àgùntàn ni ó ti mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa kí ó mú akọ tàbí abo tí kò ní àbùkù Bí ó bá ṣe pé ọ̀dọ́ àgùntàn ni ó mú, kí ó mú un wá ṣíwájú Olúwa Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú àgọ́ ìpàdé, kí àwọn ọmọ Árónì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká Kí o sì mú wá nínú ẹbọ àlàáfíà náà, fún ẹbọ tí a fi iná se sí Olúwa ọ̀rá rẹ̀ àti gbogbo ìrù rẹ̀ tí ó ní ọ̀rá, òun ni kí o mú kúrò súnmọ́ egungun ẹ̀yìn àti ọ̀rá tí ó bo ìfun lórí àti gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ lára ìfun Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí o yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa  Bí ó bá ṣe pé ewúrẹ́ ni ó mú, kí ó mú un wá ṣíwájú Olúwa Kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí Kí ó sì pa á ní iwájú àgọ́ ìpàdé Nígbà náà ni àwọn ọmọ Árónì yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká Lára ọrẹ tó mú wá, kí ó mú ọrẹ sísun fún Olúwa , gbogbo ọ̀rá tó bo nǹkan inú rẹ̀ àti ohun gbogbo tó so mọ́ ọn Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ tí a fi iná sun, ní òórùn dídùn Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ jẹ́ ti Olúwa  Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ìran tó ń bọ̀, ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀   Ẹbọ Ẹ̀ṣẹ̀ Olúwa sọ fún Mósè pé, Ṣọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé bí ẹnìkan bá sèèsì ṣe ohun tí kò yẹ kó ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa  Bí àlùfáà tí a fi òróró yàn bá ṣẹ̀, tí ó sì mú ẹ̀bi wá sórí àwọn ènìyàn, ó gbọdọ̀ mú ọmọ akọ màlúù tí kò lábùkù wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀ Kí ó mú un wá ṣíwájú Olúwa ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Olúwa Kí àlùfáà tí a fi òróró yàn mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, kí ó sì gbé e lọ sínú àgọ́ ìpàdé Kí ó ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú Olúwa , níwájú aṣọ títa ibi mímọ́ Àlùfáà yóò tún mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ náà sórí ìwo pẹpẹ tùràrí tó wà níwájú Olúwa nínú àgọ́ ìpàdé Kí ó da gbogbo ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù tókù sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ nínú akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú àti gbogbo ohun tó so mọ́ wọn Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá wọn tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà àti ọ̀rá tó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ pẹ̀lú kíndìnrín Gẹ́gẹ́ bí a se ń yọ ọ̀rá kúrò lára màlúù tí a fi rúbọ àlàáfíà àlùfáà yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ ẹbọ sísun Ṣùgbọ́n awọ màlúù àti gbogbo ara rẹ̀, àti ẹṣẹ̀, gbogbo nǹkan inú àti ìgbẹ́ rẹ̀ Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo ìyókù akọ màlúù náà ni kí ẹ gbé jáde síta lẹ́yìn ibùdó sí ibi tí a sọdi mímọ́ níbi tí à ń da eérú sí, kí ẹ sì sun wọ́n lórí iná igi, níbi eérú tí a kó jọ  Bí gbogbo àpapọ̀ ènìyàn Ísírẹ́lì bá ṣèèsì ṣẹ̀, tí wọ́n sì se ohun tí kò yẹ kí wọ́n ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa , bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àpapọ̀ ènìyàn náà kò mọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n jẹ̀bi Nígbà tí wọ́n bá mọ̀, gbogbo ìjọ ènìyàn yóò mú akọ màlúù wá sí àgọ́ ìpàdé gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Kí àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì gbé ọwọ́ lórí akọ ọmọ màlúù náà níwájú Olúwa Kí àlùfáà tí a fi òróró yàn sì mú díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ akọ ọmọ màlúù náà wá sínú àgọ́ ìpàdé Kí ó ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọn ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú Olúwa níbi aṣọ títa ẹnu ọ̀nà Kí ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ náà sórí ìwo pẹpẹ tó wà níwájú Olúwa nínú àgọ́ ìpàdé Ìyòókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí ó dà sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá kúrò lára rẹ̀, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ Kí ó sì ṣe akọ ọmọ màlúù yìí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣe akọ màlúù tó wà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ṣe ètùtù fún wọn, á ó sì dárí jìn wọ́n Lẹ́yìn náà ni yóò sun màlúù yìí lẹ́yìn ibùdó, yóò sì sun ún gẹ́gẹ́ bó se sun màlúù àkọ́kọ́ Èyí ni ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ijọ ènìyàn Ísírẹ́lì  Bí olórí kan bá ṣèèṣì ṣẹ̀ láìmọ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò yẹ kí ó ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó jẹ̀bi Nígbà tí a bá sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, ó gbọdọ̀ mú akọ ewúrẹ́ tí kò ní àbùkù wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ̀ Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lórí ewúrẹ́ náà, kí ó sì pa á níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun níwájú Olúwa Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Lẹ́yìn èyí, kí àlùfáà ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, kí ó sì da ẹ̀jẹ̀ yóòkù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ Kí ó sun gbogbo ọ̀rá rẹ̀ lórí pẹpẹ bí ó se sun ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹsẹ ọkùnrin náà, a ó sì dárí jìn-ín  Bí ènìyàn nínú àwọn ará ìlú bá ṣèèṣì ṣẹ̀ láìmọ̀ tí ó sì se ohun tí kò yẹ sí ọkan nínú àwọn òfin Olúwa , ó jẹ̀bi Nígbà tí a bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, ó gbọdọ̀ mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbùkù wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lórí ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó sì pa á níbi ẹbọ sísun Àlùfáà yóò sì ti ìka rẹ̀ bọ́ ẹ̀jẹ̀ náà, yóò fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, kí ó sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá ẹran náà gẹ́gẹ́ bó ṣe yọ ọ̀rá ẹran fún ọrẹ àlàáfíà Kí àlùfáà sì sun ọ̀rá yìí lórí pẹpẹ bí òórùn dídùn sí Olúwa Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, a ó sì dárí jìn-ín  Bí ó bá mú ọ̀dọ́-àgùntàn wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ó mú abo tí kò lábùkù Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun Àlùfáà yóò sì ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, yóò sì fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóò sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ bó ti yọ ọ̀rá lára ọ̀dọ́-àgùntàn ọrẹ àlàáfíà, àlùfáà yóò sì sun ún ní orí pẹpẹ, lórí ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa Báyìí ni àlùfáà yóò se ètùtù fún ẹni náà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀, a ó sì dáríjìn-ín Ẹbọ Ẹ̀bi  Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé kò sọ̀rọ̀ nígbà tí a bi í ní gbangba pé kó jẹ̀ẹ́rí nípa nǹkan tó rí tàbí nǹkan tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan, a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù ú  Tàbí bí ẹnìkan bá fọwọ́ kan ohun tí a kà sí àìmọ́ yálà òkú ẹranko aláìmọ́ tàbí òkú ẹran ọ̀sìn aláìmọ́ tàbí òkú ẹ̀dá yòówù tó ń rìn lórí ilẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, ó ti di aláìmọ́, ó sì ti jẹ̀bi  Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ ti ènìyàn-ohunkóhun tó lè mú ni di aláìmọ́-bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, nígbà tí ó bá mọ̀ nípa rẹ̀ yóò jẹ̀bi  Tàbí bí ẹni kan bá búra láti ṣe ohun kan láì ronú lé e lórí, yálà ohun tó dára tàbí ohun búburú, nínú ọ̀rọ̀ yòówù tó ti búra láì kíyèsí ara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò mọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kó rí, nígbà tó bá mọ̀ yóò jẹ̀bi  Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ̀bi ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ irú ọ̀nà tó ti dẹ́ṣẹ̀ àti pé gẹ́gẹ́ bí ìtanràn fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ó gbọdọ̀ mú abo àgùntàn tàbí abo ewúrẹ́ láti inú agbo ẹran wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀  Bí kò bá lágbára àti mú ọ̀dọ́-àgùntàn wá, kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ìtanràn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀-ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èkejì fún ẹbọ sísun Kí ó kó wọn wá fún àlùfáà tí yóò kọ́kọ́ rúbọ ẹ̀ṣẹ̀ kí ó yín in lọ́rùn, ṣùgbọ́n kí ó má já orí rẹ̀ tan, kí ó sì wọ́n díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí ó ro sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wá rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà, yóò sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, a ó sì dárí jìn-ní  Bí ó bá sì jẹ́ pé kò ní agbára àti mú àdàbà méjì tàbi ọmọ ẹyẹlẹ́ méjì wá, kí ó mú ìdá mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúná dáradára wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, kò gbọdọ̀ fi òróró tàbí tùràrí sí i nítorí pé ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Kí ó gbé e wá sí ọ̀dọ̀ àlùfáà, àlùfáà yóò sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà fún èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, a ó sì dárí jìn-ní   Olúwa sọ fún Mósè pé Nígbà tí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ ìrékọjá tí ó sì ṣe láìmọ̀ ní ti àwọn ohun mímọ́ Olúwa , kí ó mú àgbò láti inú agbo ẹran wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ìtanràn, àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ Ẹbọ ẹ̀bi ni Kí ó ṣe àtúnṣe nítorí ohun tí ó ti kùnà láti ṣe ní ti àwọn ohun mímọ́ Olúwa , kí ó sì fi ìdá márùn-ún kún iye ohun tí ó kùnà láti ṣe nípa ohun mímọ́ Olúwa kí ó sì kó gbogbo rẹ̀ fún àlùfáà, ẹni tí yóò ṣe ètùtù fún un pẹ̀lú àgbò fún ẹbọ ẹ̀bi, a ó sì dárí jìn-ní Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kó yẹ ko ṣe sí ọ̀kan nínú òfin Olúwa , bí kò tilẹ̀ mọ̀, ó jẹ̀bi, yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kí ó mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá sọ́dọ̀ àlùfáà, fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́ Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, fún àṣìṣe tí ó ṣe láìmọ̀, a ó sì dári jìn-ní Ẹbọ ẹ̀bi ni ó ti jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀ sí Olúwa Òfin Ẹbọ Sísun Olúwa sọ fún Mósè pé Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe àìsòótọ́ sí Olúwa nípa títan ẹnìkejì rẹ̀ lórí ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ tàbí tí wọ́n fi pamọ́ sí i lọ́wọ́, tàbí bí ó bá jalè, tàbí kí ó yan ẹnìkejì rẹ̀ jẹ, tàbí kí ó rí ohun tó sọnù he tó sì parọ́ tàbí kí ó búra èké, tàbí kí ó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ kan, irú èyí tí ènìyàn lè ṣẹ̀ Bí ó bá dẹ́ṣẹ̀ báyìí tó sì jẹ̀bi, ó gbọdọ̀ dá ohun tó jí tàbí ohun tó fi agbára gbà, tàbí ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, tàbí ohun tó sọnù tó rí he, tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí Ó gbọdọ̀ dá gbogbo rẹ̀ padà ní pípé, kí ó fi ìdá márùn ún iye rẹ̀ kún, kí ó sì dá gbogbo rẹ̀ padà fún ẹni tí ó ni í, ní ọjọ́ tó bá ń rú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀ Fún ìtanràn rẹ̀, ó gbọdọ̀ mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá fún àlùfáà, àní ṣíwájú Olúwa , ọrẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ àgbò aláìlábùkù, tó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́ Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un ètùtù ìwẹ̀nùmọ́ níwájú Olúwa , a ó sì dárí jìn-ní nítorí ohun tó ti ṣe tó sì mú-un jẹ̀bi Olúwa sọ fún Mósè pé Pàṣẹ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé Èyí ni ìlànà fún ẹbọ sísun ẹbọ sísun gbọdọ̀ wà lórí pẹpẹ láti alẹ́ di òwúrọ̀, kí iná sì máa jó lórí pẹpẹ kí àlùfáà sì wọ èwù funfun rẹ̀ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ lára rẹ̀, yóò sì kó eérú tó wà nibi ẹbọ sísun tí iná ti jó lórí pẹpẹ, sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ Nígbà náà ni yóò bọ́ aṣọ rẹ̀, yóò sì wọ òmíràn, yóò wá gbé eérú náà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tí a kà sí mímọ́ Iná tó wà lórí pẹpẹ gbọdọ̀ máa jó, kò gbọdọ̀ kú, ní àràárọ̀ ni kí àlùfáà máa to igi si, kí ó sì to ẹbọ sísun sórí iná, kí ó sì máa sun ọ̀rá ẹran ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ Iná gbọdọ̀ máa jó lórí pẹpẹ títí, kò gbọdọ̀ kú Ìwọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí àwọn ọmọ Árónì gbé ẹbọ sísun náà wá ṣíwájú Olúwa níwájú pẹpẹ Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kíkúná dáradára àti òróró pẹ̀lú gbogbo tùràrí tó wà lórí ẹbọ ohun jíjẹ náà kí ó sì sun ẹbọ ìrántí náà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò jẹ ìyókù ṣùgbọ́n wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́ láì sí máa wú máa wú ohun tí n mú àkàrà wú nínú rẹ̀ ní ibi mímọ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé ni kí wọn ó ti jẹ ẹ́ Ẹ má ṣe ṣè é pẹ̀lú yíìsìtì Èmi ti fún àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nínú ẹbọ tí a fi iná sun sí mi! Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe jẹ́ Èyíkéyí nínú àwọn ọmọkùnrin ìran Árónì ló le jẹ ẹ́ Èyí ni ìpín rẹ tí ó gbọdọ̀ máa ṣe déédé lára àwọn ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa láti ìrandíran Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́ Olúwa sọ fún Mósè pé, Èyí ni ọrẹ tí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa ní ọjọ́ tí a bá fi òróró yan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ìdámẹ́wàá òsùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára fún ẹbọ ohun jíjẹ lójoojúmọ́, ìdajì rẹ̀ ní àárọ̀ àti ìdajì rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ Ẹ pèsè rẹ̀ pẹ̀lú òróró nínú àwo fífẹ̀, ẹ pò ó pọ̀ dáradára, kí ẹ sì gbé ọrẹ ohun jíjẹ náà wá ní ègé kéé-kèè-kéé bí òórùn dídùn sí Olúwa Ọmọkùnrin Árónì tí yóò rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a fi òróró yàn ni yóò rú ẹbọ náà Ó jẹ́ ìpín ti Olúwa títí láé, wọn sì gbọdọ̀ sun ún pátapáta Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ ti àlùfáà ni wọ́n gbọdọ̀ sun pátapáta, wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ Olúwa sọ fún Mósè pé Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ Ọkùnrin Wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kí ẹ sì pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú Olúwa níbi tí ẹ ti ń pa ẹran ẹbọ sísun, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ Àlùfáà tó rú ẹbọ náà ni kí ó jẹ ẹ́, ibi mímọ́ ni kí ó ti jẹ ẹ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́, bí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ bá sì ta sí ara aṣọ kan, ẹ gbọdọ̀ fọ̀ ọ́ ní ibi mímọ́ Ẹ gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí ẹ fi ṣe ẹran náà, ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìkòkò idẹ ni ẹ fi ṣe é, ẹ gbọdọ̀ bó o, kí ẹ sì fi omi sìn ín dáradára Gbogbo ọkùnrin ní ìdílé àlùfáà ló lè jẹ ẹ́, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kankan, èyí tí wọ́n bá mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú àgọ́ ìpàdé láti fi ṣe ètùtù ní ibi mímọ́, sísun ni kí ẹ sun ún Òfin Ẹbọ Ẹ̀bi  Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún rírú ẹbọ ẹ̀bi, tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ Níbi tí wọn ti ń pa ẹran ẹbọ sísun ni kí ẹ ti pa ẹran ẹbọ ẹ̀bi, kí ẹ sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ ni kí ẹ sun, ọ̀rá ìrù rẹ̀ àti ọ̀rá tó bo nǹkan inú rẹ̀ Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti ọ̀rá to bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín Àlùfáà yóò sun wọ́n lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa Ẹbọ ẹ̀bi ni Gbogbo ọkùnrin ní ìdílé àlùfáà ló lè jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ  Òfin yìí kan náà ló wà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi méjèèjì jẹ́ tí àlùfáà, tó fi wọ́n ṣe ètùtù Àlùfáà tó rúbọ sísun fún ẹnikẹ́ni le è mú awọ ẹran ìrúbọ náà Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ tí a bá yan lórí ààrò tàbí tí a bá ṣè nínú páànù tàbí nínú àwo fífẹ̀ jẹ́ ti àlùfáà tí ó rúbọ náà Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹbọ ohun jíjẹ yálà a fi òróró pò ó tàbí èyí tó jẹ́ gbígbẹ, wọ́n jẹ́ ti gbogbo ọmọ Árónì  Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún ọrẹ àlàáfíà tí ẹnikẹ́ni bá gbé wá ṣíwájú Olúwa  Bí ẹni náà bá gbé e wá gẹ́gẹ́ bí àfihàn ọkàn ọpẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọpẹ́ yìí, ó gbọdọ̀ mú àkàrà aláìwú tí a fi òróró pò wá àti àkàrà aláìwú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a dà òróró sí àti àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúná dáradára tí a fi òróró pò ṣe Pẹ̀lú ọrẹ àlàáfíà rẹ̀, kí ó tún mú àkàrà wíwú wá fún ọpẹ́, kí ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú oríṣìíríṣìí ọrẹ àlàáfíà rẹ wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún Olúwa , ó jẹ́ tí àlùfáà tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà Ẹran ọrẹ àlàáfíà ti ọpẹ́ yìí ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ ní ọjọ́ gan-an tí wọ́n rúbọ, kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ẹran kankan kù di àárọ̀ ọjọ́ kéjì  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé ó mú ọrẹ wá, nítorí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ tàbí kí ó jẹ́ ọrẹ àtinúwá, wọn yóò jẹ ẹbọ náà ní ọjọ́ tí wọ́n rúbọ yìí, ṣùgbọ́n wọ́n lè jẹ èyí tó ṣẹ́kù ní ọjọ́ kejì Gbogbo ẹran tó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta ní ẹ gbọdọ̀ sun Bí ẹ bá jẹ ọ̀kankan nínú ẹran ọrẹ àlàáfíà ní ọjọ́ kẹta, kò ni jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà A kò ní í kà á sí fún ẹni tó rúbọ náà, nítorí pé ó jẹ́ àìmọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sì jẹ ẹ́, ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù  Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tí ó bá ti kan ohun tí a kà sí àìmọ́, sísun ni kí ẹ sun ún Ẹnikẹ́ni tí a ti kà sí mímọ́ le è jẹ nínú ẹran tí ó kù Ṣùgbọ́n bí ẹni tí kò mọ́ bá jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tí ó jẹ́ tí Olúwa , a ó ge irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀ Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun aláìmọ́ yálà ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ẹranko aláìmọ́, ohun àìmọ́ yówù kí ó jẹ́ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ìríra, tí ó sì tún jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tó jẹ́ ti Olúwa , a ó gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ   Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Ẹ má ṣe jẹ ọ̀rá mààlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́ Ẹ lè lo ọ̀rá ẹran tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko ìgbẹ́ pa, fún nǹkan mìíràn, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ọ̀rá ẹran tí a fi rúbọ sísun sí Olúwa ni ẹ gbọdọ̀ gé kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀ Ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tàbí ẹran ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀, a ó ge ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀   Olúwa sọ fún Mósè pé Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, Ẹnikẹ́ni tó bá mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa Pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀ ni kí ó fi mú ọrẹ tí a fi iná sun wá fún Olúwa , kí ó mú ọ̀rá àti igẹ̀, kí ó sì fi igẹ̀ yìí níwájú Olúwa bí ọrẹ fífí Àlùfáà yóò sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ ṣùgbọ́n igẹ̀ ẹran náà jẹ́ ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí ẹ fún àlùfáà ní itan ọ̀tún lára ọrẹ àlàáfíà yín gẹ́gẹ́ bí ìpín tiyín fún àlùfáà Ọmọ Árónì ẹni tí ó rúbọ ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà ni kí ó ni itan ọ̀tún gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀ Nínú ọrẹ àlàáfíà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo ti ya igẹ̀ tí a fi àti itan tí ẹ mú wá sọ́tọ̀ fún Árónì àlùfáà àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní gbogbo ìgbà láti ọ̀dọ̀ ara Ísírẹ́lì   Èyí ni ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ nínú ẹbọ tí a finá sun sí Olúwa lọ́jọ́ tí wọ́n mú wọn wá láti sin Olúwa gẹ́gẹ́ bí àlùfáà Lọ́jọ́ tí a fi òróró yàn wọ́n, ni Olúwa ti pa á láṣẹ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fún wọn ní àwọn nǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ìgbà gbogbo fún àwọn ìran tó ń bọ̀ Nítorí náà, àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìlànà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi, ìfinijoyè àlùfáà àti ẹbọ àlàáfíà èyí tí Olúwa fún Mósè lórí òkè Sínáì lọ́jọ́ tí Olúwa pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa mú ọrẹ wọn wá fún Olúwa ni asáálẹ̀ Sínáì Ìfinijoyè Àlùfáà Árónì Àti Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Olúwa sọ fún Mósè pé, Mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, aṣọ wọn, òróró ìtasórí, akọ mààlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ tí a kó àkàrà aláìwú sínú rẹ̀ Kí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé Mósè sì ṣe bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un, gbogbo ènìyàn sì péjọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé Mósè sì sọ fún ìjọ ènìyàn pé, Èyí ni ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ pé kí á ṣe Nígbà náà ni Mósè mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá ṣíwájú, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n Ó sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Árónì, ó fi àmùrè dì í, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìgúnwà, ó sì tún wọ̀ ọ́ ni aṣọ ìlékè oyè àlùfáà tí ó ní ìgbànú tí a ṣe ọnà dáradára sí Ó fi ìgbàyà sí àyà rẹ̀, ó sì fi Úrímù àti Júmímù síbi ìgbàyà náà Ó dé e ní fìlà, ó sì fi àwo wúrà tíí ṣe adé mímọ́ ṣíwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Mósè sì fi òróró ìtasórí ya àgọ́ àti ohun gbogbo tó wà nínú rẹ̀ sí mímọ́ Ó wọ́n díẹ̀ nínú òróró yìí sórí pẹpẹ lẹ́ẹ̀meje, ó ta òróró sórí pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò àti agbada pẹ̀lú ohun tó gbé agbada yìí dúró láti lè yà á sí mímọ́, ó da díẹ̀ lára òróró ìtasórí yìí sórí Árónì, ó sì yà á sí mímọ́ Lẹ́yìn èyí ló mú àwọn ọmọ Árónì wá ṣíwájú, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n, ó fi àmùrè dì wọ́n lára, ó fi fìlà dé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Ó sì mú akọ mààlúù wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí ẹran náà Mósè pa akọ màlúù náà, ó sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí gbogbo ìwo pẹpẹ láti wẹ pẹpẹ náà mọ́ Ó da ìyóòkù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ Bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù fún un Mósè tún mú gbogbo ọ̀rá tó bo nǹkan inú, èyí tó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, ó sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ Ṣùgbọ́n akọ màlúù yìí pẹ̀lú àwọ àti ara ẹran àti ìgbẹ́ rẹ̀ ní ó sun lẹ́yìn ibùdó gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè Lẹ́yìn náà ló mú àgbò wá fún ẹbọ sísun Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà Mósè sì pa àgbò náà, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ó sì sun orí àti àwọn ègé àti ọ̀rá rẹ̀ Ó fi omi fọ gbogbo nǹkan inú àti ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó sì sun odidi àgbò náà lórí pẹpẹ bí ẹbọ sísun òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná se sí Olúwa gẹ́gẹ́ bí Olúwa tí pàṣẹ fún Mósè Ó sì mú àgbò kejì wa, èyí ni àgbò ìfinijoyè àlùfáà, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé e lórí Mósè sì pa àgbò náà, ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, ó tọ́ ọ sí ètí ọ̀tún Árónì, sórí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti ti ẹṣẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ Mósè sì tún mú àwọn ọmọ Árónì wá ṣíwájú, ó sì mú ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ó fi sí etí ọ̀tún wọn, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ yí pẹpẹ náà ká Ó mú ọ̀rá ẹran náà, ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára nǹkan inú àti èyí tó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn pẹ̀lú itan ọ̀tún Lẹ́yìn náà ló mú àkàrà aláìwú sí, èyí tó wà níwájú Olúwa àti àkàrà tí a fi òróró ṣe, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì kó gbogbo rẹ̀ sórí ọ̀rá àti itan ọ̀tún ẹran náà Ó kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí lé Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa Lẹ́yìn náà, Mósè gba gbogbo rẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó sì sun wọn lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìfinijoyè àlùfáà òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa Mósè sì mú igẹ̀ ẹran náà, èyí tó jẹ́ ìpín rẹ̀ nínú àgbò fún ìfinijoyè, ó sì fìí níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, bi Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Mósè sì mú díẹ̀ lára òróró ìtasórí àti díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ láti orí pẹpẹ, ó wọ́n sára àwọn ọmọ Árónì àti aṣọ rẹ̀, ó sì tún wọ́n sára àwọn ọmọ Árónì àti aṣọ wọn Bẹ́ẹ̀ ní Mósè ya Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ wọn sí mímọ́ Mósè sì sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, Ẹ ṣe ẹran náà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀ pẹ̀lú àkàrà tí a mú láti inú apẹ̀rẹ̀ ọrẹ ìfinijoyè àlùfáà gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó jẹ ẹ́ Kí ẹ fi iná sun ìyóòkù àkàrà àti ẹran náà Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje, títí tí ọjọ́ ìfinijoyè àlùfáà yín yóò fi pé, nítorí pé ìfinijoyè àlùfáà yín yóò gba ọjọ́ méje gbáko Ohun tí a ṣe lónìí jẹ́ ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ láti ṣe ètùtù fún yín Ẹ gbọdọ̀ wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé lọ́sàn án àti lóru fún ọjọ́ méje kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa fẹ́, kí ẹ má ba à kú, nítorí ohun tí Olúwa pa láṣẹ fún mi ni èyí Báyìí ni Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo tí Olúwa pa láṣẹ láti ẹnu Mósè Àwọn Àlùfáà Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ní ọjọ́ kẹjọ, Mósè pe Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì Ó sọ fún Árónì pé, Mú akọ ọmọ màlúù kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò kan fún ẹbọ sísun, kí méjèèjì jẹ́ aláìlábùkù, kí o sì mú wọn wá sí iwájú Olúwa Kí o sì sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé, Ẹ mú òbúkọ kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọmọ màlúù àti ọ̀dọ́ àgùntàn kan, kí méjèèjì jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun, àti akọ màlúù kan àti àgbò kan fún ẹbọ àlàáfíà àti ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò láti fi rú ẹbọ ní iwájú Olúwa Nítorí pé Olúwa yóò farahàn yín ní òní   Wọ́n kó gbogbo àwọn nǹkan tí Mósè pa láṣẹ wá sí iwájú àgọ́ ìpàdé, gbogbo ìjọ ènìyàn sì súnmọ́ tòsí, wọ́n sì dúró níwájú Olúwa Nígbà náà ni Mósè wí pé, Ohun tí Olúwa pa láṣẹ fún yín láti ṣe nìyìí, kí ògo Olúwa bá à lè farahàn yín Mósè sọ fún Árónì pé, Wá sí ibi pẹpẹ kí o sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ àti fún àwọn ènìyàn rú ẹbọ ti àwọn ènìyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ Árónì sì wá síbi pẹpẹ, ó pa akọ ọmọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀ Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ náà wá fún un, ó sì ti ìka ọwọ́ rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí ìwo pẹpẹ, ó sì da ìyóòkù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìṣalẹ̀ pẹpẹ Ó sun ọ̀rá, kíndìnrín àti ọ̀rá tó bo ẹ̀dọ̀, èyí tó mú láti inú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, lórí pẹpẹ bí Olúwa ti pá láṣẹ fún Mósè Ó sì sun ara ẹran àti awọ rẹ̀ ní ẹ̀yìn ibùdó Lẹ́yìn èyí ó pa ẹran tó wà fún un ẹbọ sísun Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ fún, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká Wọ́n sì ń mú ẹbọ sísun náà fún un ní ègé kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú orí rẹ̀, ó sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ Ó fọ nǹkan inú rẹ̀ àti ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó sun wọ́n lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ Árónì mú ẹbọ tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn wá Ó mú òbúkọ èyí tó dúró fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn ó sì pa á, ó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti àkọ́kọ́ Ó mú ẹbọ sísun wá, ó sì rú u gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a fi lélẹ̀ Ó tún mu ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní àfikún ẹbọ sísun tí àárọ̀ Ó pa akọ màlúù àti àgbò bí ẹbọ àlàáfíà fún àwọn ènìyàn Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà fún un, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká Ṣùgbọ́n ọ̀rá akọ màlúù àti àgbò náà ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, básí ọ̀rá, ọ̀rá kíndìnrín, àti ọ̀rá tó bo ẹ̀dọ̀ gbogbo rẹ̀ ni wọ́n kó lórí igẹ̀ ẹran náà Árónì sì sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ Árónì fí igẹ̀ àti itan ọ̀tún ẹran náà níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì bí Mósè ṣe pa á láṣẹ Árónì sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn ènìyàn, ó sì súre fún wọn Lẹ́yìn tó sì ti rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà, ó sọ̀kalẹ̀ Mósè àti Árónì sì wọ inú àgọ́ ìpàdé Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn ènìyàn, ògo Olúwa sì farahàn sí gbogbo ènìyàn, Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa , ó sì jó ẹbọ sísun àti ọ̀rá orí pẹpẹ Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì rí èyí wọ́n hó ìhó ayọ̀, wọ́n sì dojú bolẹ̀ Àṣọtẹ́lẹ̀ nípa Ìbí Jòhánù onítẹ̀bọmi Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti dáwọ́lé títo àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì jọ lẹ́sẹẹsẹ, èyí tí ó ti múlẹ̀ ṣinṣin láàárin wa, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà tí ó ṣe ojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ti fi lé wa lọ́wọ́ Nítorí náà, ó sì yẹ fún èmi pẹ̀lú láti kọ̀wé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ bí mo ti wádìí ohun gbogbo fínnífínní láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Tìófílù ọlọ́lá jùlọ, kí ìwọ kí ó le mọ òtítọ́ ohun wọ̀n-ọn-nì tí a ti kọ́ ọ Nígbà ọjọ́ Hérọ́dù ọba Jùdéà, Àlùfáà kan wà, ní ipa ti Ábíà, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sakaráyà aya rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìrin Árónì, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Èlísábẹ́tì Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí tí Èlísábẹ́tì yàgàn àwọn méjèèjì sì di arúgbó Ó sì ṣe, nígbà tí ó ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà níwájú Ọlọ́run níipaṣẹ̀ tirẹ̀ Bí ìṣe àwọn àlùfáà, ipa tirẹ̀ ni láti máa fi tùràrí jóná, nígbà tí ó bá wọ inú tẹ́ḿpìlì Olúwa lọ Gbogbo Ìjọ àwọn ènìyàn sì ń gbàdúrà lóde ní àkókò sísun tùràrí Ańgẹ́lì Olúwa kan sì fi ara hàn án, ó dúró ní apá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí Nígbà tí Sakaráyà sì rí i, orí rẹ̀ wúlé, ẹ̀rù sì bà á Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì náà wí fún un pé, Má bẹ̀rù, Sakaráyà nítorí tí àdúrà rẹ gbà Èlísábẹ́tì aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jòhánù Òun yóò sì jẹ́ ayọ̀ àti ìdùnnú fún ọ ènìyàn púpọ̀ yóò sì yọ̀ sí ìbí rẹ Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí-wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí-líle yóò sì kún fún Èmí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá Òun ó sì yí ènìyàn púpọ̀ padà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí Olúwa Ọlọ́run wọn Ẹ̀mí àti agbára Èlíjàh ni Olúwa yóò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọ́ràn sí ọgbọ́n àwọn olóòótọ́ kí ó le pèṣè àwọn ènìyàn tí a múra sílẹ̀ de Olúwa Sakaráyà sì wí fún áńgẹ́lì náà pé, Àmì wo ni èmi ó fi mọ èyí Èmi sá ti di àgbà, àti Èlísábẹ́tì aya mi sì di arúgbó Ańgẹ́lì náà sì dáhùn ó wí fún un pé, Èmi ni Gébúrẹ́lì, tí máa ń dúró níwájú Ọlọ́run èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìyìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá Sì kíyèsí i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn Àwọn ènìyàn sì ń dúró de Sakaráyà, ẹnu sì yà wọ́n nítorí tí ó pẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì Nígbà tí ó sì jáde wá, òun kò le bá wọn sọ̀rọ̀ Wọn sì kíyèsí wí pé ó ti rí ìran nínú tẹ́ḿpílì ó sì ń se àpẹẹrẹ sí wọn, nítorí tí ó yadi Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ pé, ó lọ sí ilé rẹ̀ Lẹ́yìn èyí ni Èlísábẹ́tì aya rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́ ní oṣù márùn-ún, ó ní, Ó sì wí pé Báyìí ni Olúwa ṣe fún mi ní ọjọ́ tí ó ṣíjú wò mí, láti mú ẹ̀gàn mi kúrò láàrin àwọn ènìyàn Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán áńgẹ́lì Gébúríẹ́lì sí ìlú kan ní Gálílì, tí à ń pè ní Násárẹ́tì, sí wúndíá kan tí a ṣè lérí láti fẹ́ fún ọkùnrin kan, tí a ń pè ní Jóṣéfù, ti ìdílé Dáfídì orúkọ wúndíá náà a sì máa jẹ́ Màríà Ańgẹ́lì náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, Àlààáfíà, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ńbẹ pẹ̀lú rẹ Ṣùgbọ́n ọkàn Màríà kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kínni èyí Ṣùgbọ́n àńgẹ́lì náà wí fún un pé, Má bẹ̀rù, Màríà nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run Ìwọ óò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní JÉSÙ Òun ó pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún Yóò sì jọba lórí ilé Jákọ́bù títí láé ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun Nígbà náà ni Màríà bèèrè lọ́wọ́ ańgẹ́lì náà pé, Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tii mọ ọkùnrin Ańgẹ́lì náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, àti agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò sìji bò ọ́ Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é Sì kíyèsí i, Èlísábẹ́tì ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọ kùnrin kan ní ògbólògbó rẹ̀ èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe Màríà sì dáhùn wí pé, wò ó ọmọ-ọ̀dọ̀ Olúwa kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ Ańgẹ́lì náà sì fi í sílẹ̀ lọ Ní ijọ́ wọ̀nyí ni Màríà sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Júdà Ó sì wọ ilé Sakaráyà lọ ó sì kí Èlísabẹ́tì Ó sì ṣe, nígbà tí Èlísábẹ́tì gbọ́ kíkí Màríà, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀ Èlísábẹ́tì sì kún fún Èmí mímọ́ Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, Alúbùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkúnfún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀ Alábùkúnfún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́ nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ Màríà sì dáhùn, ó ní Ọkàn mi yin Olúwa lógo, Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi Nítorí tí ó ṣíjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀ Sá wò ó, láti ìsinsìn yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkúnfún Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀ Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ láti ìrandíran Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀ Ó ti tú àwọn onígberaga ká ní ìrònú ọkàn wọn Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn, Ó sì gbé àwọn onírẹ̀lè lékè Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebí ń pa ó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo Ó ti ran Ísíráẹ́lì ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́, Ní ìrántí àánú rẹ̀ sí Ábúráhámù àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa, àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa Màríà sì jókòó tì Èlísábétì níwọ̀n oṣù mẹ́ta, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀ Nígbà tí ọjọ́ Èlísabẹ́tì pé wàyí tí yóò bí ó sì bí ọmọkùnrin kan Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀ Ó sì ṣe, ní ijọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sakaráyà, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀ Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, Bẹ́ẹ̀ kọ́! Jòhánù ni a ó pè é Wọ́n sì wí fún un pé, Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí bàbá rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, Jòhánù ni orúkọ rẹ̀ Ẹnu sì ya gbogbo wọn Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Jùdéà Ó sì jẹ́ ohun ìyọnu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n ń wí pé, Irú ọmọ kínni èyí yóò jẹ́ Nítirí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀ Sakaráyà baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì ṣọtẹ́lẹ̀, ó ní Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì Nítorí tí ó ti bojúwò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè, Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún wa Ní ilé Dáfídì ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ , Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórira wá Láti ṣe àánú tí ó ti lérí fún àwọn baba wa, Àti láti rántí májẹ̀mu rẹ̀ mímọ́, ìbúra tí ó ti bú fún Ábúráhámù baba wa, láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, Kí àwa kí ó lè máa sìn ín láìfòyà, Ní mímọ́ ìwà àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́ Nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe Láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí ìyọ́nú Ọlọ́run wà nípa èyí tí ìlà-òrùn láti òkè wá bojúwò wá, Láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó jókòó ní òkùnkùn àti ní òjìjì ikú Àti láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà àlààáfíà Ọmọ náà sì dàgbà, ó sì le ní ọkàn, ó sì ń gbé ní ijù títí ó fi di ọjọ́ ìfihàn rẹ̀ fún Ísírẹ́lì Jésù Rán Àádọ́rin Ọmọ-Ẹ̀yìn Jáde Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn míràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjìméjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkárarẹ̀ yóò sì dé Ó sì wí fún wọn pé, Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀ Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́ àgùntàn sáàrin ìkookò Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà Ní ilékílé tí ẹ̀yín bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, Àlààáfíà fún ilé yìí! Bí ọmọ àlààáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín E dúró sínú ilé yẹn, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fifún yín nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i, Ẹ má ṣe ṣí láti ilé dé ilé Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín! Ṣùgbọ́n ní ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, tí wọn kò bá sì gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá sì jáde sí ìgboro ìlú náà, kí ẹ̀yin sì wí pé, Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù dẹ̀dẹ̀ sí yín! Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Sódómù ní ìjọ́ náà, ju fún ìlú náà lọ Ègbé ni fún ìwọ, Kórásínì! Ègbé ni fún ìwọ Bẹtiṣáídà! Nítorí ìbáṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tírè àti Ṣídónì, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tírè àti Sídónì nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ Àti ìwọ, Kápánáúmù, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ Ó sì wí fún wọn pé, Èmí rí Sátánì ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá Kíyèsí i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèé mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá kò sì sí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ sí èyí, pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run! Ní wákàtí kan náà Jésù yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́ bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sáà yẹ ní ojú rẹ Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi kò sì sí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apákan Ó ní, Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn Sì kíyèsí i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, Olùkọ́, kínni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun Ó sì bi í pé, Kí ni a kọ sínú ìwé òfin Bí ìwọ ti kà á Ó sì dáhùn wí pé,  Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ àti, Ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ   Ó sì wí fún un pé, Ìwọ́ dáhùn rere ṣe èyí, ìwọ ó sì yè Ṣùgbọ́n ó ń fẹ́ láti da ara rẹ̀ láre, ó wí fún Jésù wí pé, Ta ha sì ni ẹnìkejì mi Jésù sì dáhùn ó wí pé, Ọkùnrin kan ń ti Jerúsálémù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán Ní kòńgẹ́ àkókò yìí ni àlùfáà kan sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ lọ́nà náà nígbà tí ó sì rí i ó kọjá lọ níhà kejì Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọmọ Léfì kan pẹ̀lú, nígbà tí ó dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó kọjá lọ níhà kejì Ṣùgbọ́n ará Samáríà kan, bí ó ti ń re àjò, ó dé ibi tí ó gbé wà nígbà tí ó sì rí i, àánú ṣe é Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì di ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí i, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti òun tìkalárarẹ̀, ó sì mú un wá sí ilé èrò, a sì ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀ Nígbà tí ó sì lọ ní ijọ́ kejì, ó fi owó idẹ méjì fún olórí ilé èrò ó sì wí fún un pé, Má a tọ́jú rẹ̀ ohunkóhun tí ìwọ bá sì ná kún un, nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san án fún ọ Nínú àwọn mẹ́tẹ̀èta wọ̀nyí, tani ìwọ rò pé ó jẹ́ ẹnìkejì ẹni tí ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà Ó sì dáhùn wí pé, Ẹni tí ó ṣàánú fún un Jésù sì wí fún un pé, Lọ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́! Ó sì se, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Mátà sì gbà á sí ilé rẹ̀ Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Màríà tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹṣẹ̀ Jésù, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ Ṣùgbọ́n Mátà ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkàn ṣe ìránṣẹ́ Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́ Ṣùgbọ́n Jésù sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, Mátà, Mátà, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀ Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Màríà sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀ Jésù Ń Kọ́ Ẹ̀kọ́ Nípa Àdúrà Bí ó ti ń gbàdúrà ní ibi kan, bí ó ti dákẹ́, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, Olúwa, kọ́ wa bí a ti ń gbàdúrà, bí Jòhánù ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Ó sì wí fún wọn pé, Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ máa wí pé  Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ Kí ìjọba rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe, bí i ti ọrun, Bẹ́ẹ̀ ni ní ayé Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lójoojúmọ́ Kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá nítorí àwa tìkarawa pẹ̀lú a máa dáríji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbésè, Má sì fà wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ bìlísì   Ó sì wí fún wọn pé, Ta ni nínú yín tí yóò ní ọ̀rẹ́ kan, tí yóò sì tọ̀ ọ́ lọ láàrin ọ̀gànjọ́, tí yóò sì wí fún un pé, Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù àkàrà mẹ́ta Nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti àjò dé sọ́dọ̀ mi, èmi kò sì ní nǹkan tí èmi ó gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀ Tí òun ó sì gbé inú ilé dáhùn wí fún un pé, Má yọ mí lẹ́nu a ti sé ìlẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi si ń bẹ lórí ẹní pẹ̀lú mi èmi kò lè dìde fi fún ọ! Mo wí fún yín, bí òun kò tilẹ̀ ti fẹ́ dìde kí ó fifún un nítorí tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí àwíìyánu rẹ̀, yóò dìde, yóò sì fún un pọ̀ tó bí ó ti ń fẹ́ Èmí sì wí fún yín, Ẹ bèèrè, a ó sì fifún un yín ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí ẹ kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè, yóò rí gbà ẹni tí ó sì ń wá kiri, yóò rí àti ẹni tí ó kànkùn ni a ó ṣí i sílẹ̀ fún Ta ni baba nínú yín tí ọmọ rẹ̀ yóò bèèrè ẹja, tí yóò fún un ní ejò dípò ẹja Tàbí bí ó sì bèèrè ẹ̀yin, tí yóò fún un ní àkéekée Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ó jẹ́ ènìyàn búburú bá mọ bí a ti í fi ẹ̀bùn dáradára fún àwọn ọmọ yín mélóméló ha ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi Ẹ̀mí-Mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tí ó bèèrè lọ́dọ̀ rẹ̀! Ó sì ń lé ẹ̀mí ẹ̀sù kan jáde, tí ó sì yadi Nígbà tí ẹ̀mí ẹ̀ṣù náà jáde, odi sọ̀rọ̀ ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn wí pé, Nípa Béélísébúbù olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde Àwọn ẹlòmíràn sì ń dán an wò, wọ́n ń fẹ́ àmì lọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀run wá Ṣùgbọ́n òun mọ ìrò inú wọn, ó wí fún wọn pé, Gbogbo ìjọba tí ó ya ara rẹ̀ ní ipá, ni a ń sọ di àhoro ilé tí ó sì ya ara rẹ̀ nípá yóò wó Bí Sàtánì sì yapa sí ara rẹ̀, ìjọba rẹ̀ yóò ha ṣe dúró Nítorí ẹ̀yin wí pé, nípa Béélísébúbù ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde Bí ó ba ṣe pé nípa Béélísébúbù ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù jáde, nípa tani àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde, nítorí náà àwọn ni yóò ṣe onídájọ́ yín Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pé Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run dé bá yín tán Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni tí ó ní agbára jù ú bá kọlù ú, tí ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ a gba gbogbo ìhámọ́ra rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé lọ́wọ́ rẹ̀, a sì pín ìkógun rẹ̀ Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, ó lòdì sí mi ẹni tí kò bá sì bá mi kópọ̀, ó fọ́nká Nígbà tí ẹ̀mí àìmọ́ bá jáde kúrò lára ènìyàn, a máa rìn kiri ní ibi gbígbẹ, a máa wá ibi ìsinmi nígbà tí kò bá sì rí, a wí pé, Èmi yóò padà lọ sí ilé mi ní ibi tí mo gbé ti jáde wá Nígbà tí ó bá sì dé, tí ó sì rí tí a gbá a, tí a sì ṣe é ní ọ̀sọ́ Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun tìkárarẹ̀ lọ wá wọn yóò wọlé, wọn yóò sì máa gbé níbẹ̀ ìgbẹ̀hìn ọkùnrin náà yóò sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan nahùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu! Ṣùgbọ́n oun wí pé, Nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́! Nígbà tí ìjọ ènìyàn sì ṣùjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, Ìran búburú ni èyí wọ́n ń wá àmì a kì yóò sì fi àmì kan fún un bí kò ṣe àmì Jónà wòlíì! Nítorí bí Jónà ti jẹ́ àmì fún àwọn ará Nínéfè, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọmọ-ènìyàn yóò ṣe jẹ́ àmì fún ìran yìí Ọba-bìnrin gúsù yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìran yìí, yóò sì dá wọn lẹ́bi nítorí tí ó ti ìhà ìpẹ̀kun ayé wá láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómónì sì kíyèsí i, ẹni tí ó pọ̀ju Sólómónì lọ ń bẹ níhín-ín yìí Àwọn ará Nínéfè yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn ó sì dá a lẹ́bi nítorí tí wọn ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jónà sì kíyèsíi, ẹni tí ó pọ̀jù Jónà lọ ń bẹ níhín-ín yìí Kò sí ẹnìkan, nígbà tí ó bá tan fìtílà tan, tí i gbé e sí ìkọ̀kọ̀, tàbí sábẹ́ òṣùwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọlé baà lè má a rí ìmọ́lẹ̀ Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara bí ojú rẹ bá mọ́, gbogbo ara rẹ a mọ́lẹ̀ ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá burú, ara rẹ pẹ̀lú a kún fún òkùnkùn Nítorí náà kíyèsí i, kí ìmọ́lẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ má ṣe di òkùnkùn Ǹjẹ́ bí gbogbo ara rẹ bá kún fún ìmọ́lẹ̀, tí kò ní apákan tí ó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ ni yóò ní ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí fìtílà bá fi ìtànsán rẹ̀ fún ọ ní ìmọ́lẹ̀ Bí ó sì ti ń wí, Farisí kan bẹ̀ẹ́ kí ó bá òun jẹun ó sì wọlé, ó jókòó láti jẹun Nígbà tí Farisí náà sì rí i, ẹnu yà á nítorí tí kò kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ kí ó tó jẹun Olúwa sì wí fún un pé, Ẹ̀yin Farisí a máa fẹ́ fi ara hàn bí ènìyàn mímọ́ ṣùgbọ́n, inú yín kún fún ìwà búburú àti ìrẹ́jẹ Ẹ̀yin aláìmòye, ẹni tí ó ṣe èyí tí ń bẹ lóde, òun kò ha ṣe èyí tí ń bẹ nínú pẹ̀lú Kí ẹ̀yin kúkú má a ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsii, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisí, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá mítì àti rue, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsì fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisí, àgàbàgebè! Nítorí tí ẹ̀yin fẹ́ ipò ọlá nínú sínágọ́gù, àti ìkíni ní ọjà Ègbé ni fún-un yín, nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀ Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn amòfin dáhùn, ó sì wí fún un pé, Olùkọ́, nínú èyí tí ìwọ ń wí yìí ìwọ ń gan àwa pẹ̀lú Ó sì wí pé, Ègbé ni fún ẹ̀yin amòfin pẹ̀lú, nítorí tí ẹ̀yin di ẹrù tí ó wúwo láti rù lé ènìyàn lórí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin tìkarayín kò jẹ́ fi ìka yín kan ẹrù náà Ègbé ni fún yín, nítorí tí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì, tí àwọn baba yín pa Ǹjẹ́ ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí, ẹ sì ní inú dídùn sí iṣẹ́ àwọn baba yín, nítorí tí wọn pa wọ́n, ẹ̀yin sì kọ́ ibojì wọn Nítorí èyí ni ọgbọ́n Ọlọ́run sì se wí pé, Èmi ni ó rán àwọn wòlíì àti àwọn àpósítélì sí wọn, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí wọn Kí a lè bèèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí Láti ẹ̀jẹ̀ Ábélì wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sakaráyà, tí ó ṣègbé láàrin pẹpẹ àti tẹ́ḿpìlì lóòótọ́ ni mo wí fún yín Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin amòfin, nítorí tí ẹ̀yin ti mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ kúrò ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, àwọn tí sì ń wọlé, ni ẹ̀yin ń dí lọ́wọ́ Bí ó ti ń lọ kúrò níbẹ̀, àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí bi í lọ́rọ̀ gidigidi, wọ́n sì ń yọ ọ́ lẹ́nu láti wí nǹkan púpọ̀ Wọ́n ń ṣọ́ ọ, wọ́n ń wá ọ̀nà láti rí nǹkan gbámú mọ́ ọn lẹ́nu kí wọn báà lè fi ẹ̀sùn kàn án Àwọn Ìkìlọ̀ Àti Ọ̀rọ̀ Ìyànjú Ó sì ṣe, nígbà tí àìníye ìjọ ènìyàn péjọ pọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Ẹ máa sọ́ra yín nítorí ìwúkàrà àwọn Farisí tí í ṣe àgàbàgebè Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀ Nítorí náà ohunkóhun tí ẹ̀yin sọ ní òkùnkùn, ní gbangba ni a ó ti gbọ́ ọ àti ohun tí ẹ̀yin bá sọ sí etí ní ìkọ̀kọ̀, lórí òrùlé ni a ó ti kéde rẹ̀ Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́ Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpádì lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù Ológoṣẹ́ márùn ún sáà ni a ń tà lówó idẹ wẹ́wẹ́ méjì A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀yin ní iye lórí ju ológóṣẹ́ púpọ̀ lọ Mo sì wí fún yín pẹ̀lú, Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú àwọn ènìyàn Ọmọ ènìyàn yóò sì jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú ènìyàn, a ó sẹ́ ẹ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run Àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ọmọ ènìyàn, a ó dárí rẹ̀ jìn-ín ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí rẹ̀ jìn-ín Nígbà tí wọ́n bá sì mú yín wá sí sínágọ́gù, àti síwájú àwọn olórí, àti àwọn alásẹ, ẹ má ṣe ṣàníyàn pé, báwo tàbí ohun kínni ẹ̀yin yóò fèsì rẹ̀ tàbí kínni ẹ̀yin ó wí Nítorí Ẹ̀mí mímọ́ yóò kọ́ yín ní wákàtí kan náà ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ Ọ̀kan nínú àwùjọ wí fún un pé, Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín mi ní ogún Ó sì wí fún un pé, Ọkùnrin yìí, tani ó fi mí jẹ onídájọ́ tàbí olùpí-ogúnn fún yín Ó sì wí fún wọn pé, Kíyèsára kí o sì má a sọ́ra nítorí ojúkòkòrò nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kò dúró lé ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní Ó sì pa òwe kan fún wọn, pé, ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí Ó sì wí pé, Èyí ni èmi ó ṣe èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èṣo àti ọrọ̀ mi jọ sí Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún sinmi, máa jẹ, máa mu, má a yọ̀ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó bèèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ ǹjẹ́ ti tani nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìsúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Nítorí náà mo wí fún yín pé, ẹ má ṣe ṣàníyàn nítorí ọkàn yín pé, kínni ẹ̀yin ó fi bora Ọkàn sáà ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ Ẹ kíyèsí àwọn ẹyẹ ìwò wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sáà ń bọ́ wọn mélòómélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ! Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ìgbé ayé rẹ̀ Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹyin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù Ẹ kíyèsí àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́sọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko ìgbẹ́ ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónì-ín, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la mélòómélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin oní kékeré ìgbàgbọ́ Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣàníyàn ọkàn Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀ èdè ayé lé kiri Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ nǹkan wọ̀nyí Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín Má bẹ̀rù, agbo kékeré nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fi ìjọba fún yín Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́ Nítorí ní ibi tí ìṣura yín gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yóò gbé wà pẹ̀lú Ẹ di àmùrè yín, kí fìtílà yín sì máa jó Kí ẹ̀yin tìkárayín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé pé, nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń sọ́nà lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn Bí olúwa wọn bá sì dé nígbà ìṣọ́ kejì, tàbí tí ó sì dé nígbà ìṣọ́ kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ náà Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí tí olè yóò wá, kì bá tí jẹ́ kí a já wọ inú ilé òun Nítorí náà kí ẹ̀yin múra pẹ̀lú Nítorí ọmọ ènìyàn ń bọ̀ ní wákàtí tí ẹ̀yin kò nírètí Pétérù sì wí pé, Olúwa, ìwọ́ pa òwe yìí fún wa, tàbí fún gbogbo ènìyàn Olúwa sì dáhùn wí pé, Ta ni olóòótọ́ àti ọlọ́gbọ́n ìríjú náà, tí olúwa rẹ̀ fi jẹ olórí agbo ilé rẹ̀, láti máa fi ìwọ̀n oúnjẹ wọ̀n fún wọn ní àkókò Ìbùkún ni fún ọmọ-ọ̀dọ̀ náà, nígbà tí olúwa rẹ̀ bá dé, tí yóò bá a kí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀ Lóòótọ́ ni mo wí fún yín yóò fi jẹ olórí ohun gbogbo tí ó ní Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá wí ní ọkàn rẹ̀, pé, Olúwa mi fi ìgbà bíbọ̀ rẹ̀ falẹ̀! Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́-kùnrin àti ìráṣẹ́bìnrin tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àti sí mu àmupara Olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀, àti ní wákàtí tí kò dábàá, yóò sì jẹ ẹ́ níyà gidigidi, yóò sì yan ipò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́ Àti ọmọọ̀dọ̀ náà, tí ó mọ ìfẹ́ olúwa rẹ̀, tí kò sì múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, òun ni a ó nà púpọ̀ Ṣùgbọ́n èyí tí kò mọ̀, tí ó ṣe ohun tí ó yẹ sí lílù, òun ni a ó lù níwọ̀n Nítorí ẹnikẹ́ni tí a fún ní púpọ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a ó gbé bèèrè púpọ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí a bá gbé fi púpọ̀ sí, lọ́dọ̀ rẹ ni a ó gbé bèèrè sí i Iná ni èmi wá láti sọ sí ayé kínni èmi sì ń fẹ́ bí kò ṣe kí a ti dá a ná! Ṣùgbọ́n èmi ní bamtísíìmù kan tí a ó fi bamitisí mi ara ti ń ni mí tó títí yóò fi parí! Ẹ̀yin ṣe bí àlààáfíà ni èmi wá fi sáyé Mo wí fún yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́ ṣùgbọ́n bí kò ṣe ìyapa Nítorí láti ìsinsìn yìí lọ, ènìyàn márùn-ún yóò wà ní ilé kan náà tí a ó yà ní ipa, mẹ́ta sí méjì, àti méjì sí mẹ́ta A ó ya baba nípa sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọkùnrin sí baba ìyá sí ọmọbìnrin, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, ìyá ọkọ sí ìyàwó ọmọ, àti ìyàwó ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀ Ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pẹ̀lú pé, Nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìkùukù àwọ̀sánmà tí ó ṣú ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, lọ́gán ni ẹ̀yin yóò sọ pé, Ọ̀wàrà òjò ń bọ̀, a sì rí bẹ́ẹ̀ Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúsù bá ń fẹ́, ẹ̀yin á ní, Oòrùn yóò mú, yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ Ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin le mòye ojú ọ̀run àti ti ayé Èé ha ti ṣe tí ẹ̀yin kò mọ àkókò yìí Èé ha ti ṣe tí ẹ̀yin tìkárayín kò fi ro ohun tí ó tọ́ Nígbà tí ìwọ bá bá ọ̀ta rẹ lọ sọ́dọ̀ onídàájọ́, rí i pé o bá a parí ọ̀rọ̀ ní ọ̀nà kí ó má baà fà ọ́ fún adájọ́, adájọ́ a fi ọ́ lé ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, òun a sì tì ọ́ sínú túbú Kí èmi wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀, títí ìwọ ó fi san ẹyọ owó kan tí ó bá kù! Ẹ Ronúpìwàdà Kí Ẹ Má Bà á Sègbé Àwọn kan sì wá ní àkókò náà tí ó sọ ti àwọn ará Gálílì fún un, ẹ̀jẹ̀ ẹni tí Pílátù dàpọ̀ mọ́ ti wọn Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, Ẹ̀yin ṣe bí àwọn ará Gálílì wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ará Gálílì lọ, nítorí wọ́n jẹ iru ìyà báwọ̀n-ọ́n-nì Mo wí fún yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́ bí kò se pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ Tàbí àwọn méjìdínlógún, tí ilé-ìsọ́ ní Sílóámù wólù, tí ó sì pa wọ́n, ẹ̀yin sebí wọ́n ṣe ẹlẹ́sẹ̀ ju gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní Jerúsálémù lọ Mo wí fún yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́ bí kò ṣe pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ Ó sì pa òwe yìí fún wọn pé Ọkùnrin kan ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí a gbìn sí ọgbà àjàrà rẹ̀ ó sì dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, kò sì rí nǹkan Ó sì wí fún olùsọ́gbà rẹ̀ pé, Sáàwòó, láti ọdún mẹ́ta ni èmi ti ń wá í wo èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, èmi kò sì rí nǹkan ké e lulẹ̀ èéṣe tí ó fi ń gbilẹ̀ lásán pẹ̀lú Ó sì dáhùn ó wí fún un pé, Olúwa, jọ̀wọ́ rẹ̀ lí ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi ó fi tu ilẹ̀ ìdí rẹ̀ yíká, títí èmi ó sì fi bu ìlẹ̀dú sí i Bí ó bá sì so èso, gẹ́gẹ́ bí kò bá sì so, ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí nì kí ìwọ kí ó ké e lulẹ̀   Ó sì ń kọ́ni nínú Sínágọ́gù kan ní ọjọ́ ìsinmi Sì kíyèsí i, obìnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ní ẹmí àìlera, láti ọdún méjìdínlógún wá, ẹni tí ó tẹ̀ tán, tí kò le gbé ara rẹ̀ sókè bí ó ti wù kí ó ṣe Nígbà tí Jésù rí i, ó pè é sí ọ̀dọ̀, ó sì wí fún un pé, Obìnrin yìí, a tú ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ àìlera rẹ Ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé e Lójúkan náà a sì ti sọ ọ́ di títọ́, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo Olórí sínágọ́gù sì kún fún ìrúnnú, nítorí tí Jésù múni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pé, Ijọ́ mẹ́fà ní ń bẹ tí a fi í ṣiṣẹ́ nínú wọn ni kí ẹ̀yin kí ó wá kí á ṣe dídá ara yín, kí ó má se ní ọjọ́ ìsinmi Nígbà náà ni Olúwa dáhùn, ó sì wí fún un pé, Ẹ̀yin àgàbàgebè, olúkúlùkù yín kì í tú màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò níbùso, kì í sì í fà á lọ mumi lí ọjọ́ ìsinmi Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í se ọmọbìnrin Ábúráhámù sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí sàtánì ti dè, sáà wò ó láti ọdún májìdínlógún yìí wá Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, ojú ti gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀ gbogbo ìjọ ènìyàn sì yọ̀ fún ohun ògo gbogbo tí ó ṣe láti ọwọ́ rẹ̀ wá Ó sì wí pé, Kíni ìjọba Ọlọ́run jọ Kíni èmi ó sì fi wé Ó dàbí hóró músítádì, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀ tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀ Ó sì tún wí pé, Kíli èmi ìbá fi ìjọba Ọlọ́run wé Ó dàbí ìwúkàrà, tí obìnrin kan mú, tí ó fi sínú òsùnwọ̀n ìyẹ̀fun mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ ó fi di wíwú Ó sì ń la àárin ìlú àti ìletò lọ, ó ń kọrin, ó sì ń rìn lọ sí ìhà Jerúsálémù Ẹnìkan sì bi í pé, Olúwa, díẹ̀ ha ni àwọn tí a ó gbàlà Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ làkàkà láti gba ojú ọ̀nà tóóró wọlé nítorí mo wí fún yín, ènìyàn púpọ̀ ni yóò wá ọ̀nà láti wọ̀ ọ́, wọn kì yóò sì lè wọlé Nígbà tí baálé ilé bá dìde lẹ́ẹ̀kan fù ú, tí ó bá sí ìlẹ̀kùn ẹ̀yin ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lóde, tí ẹ ó máa kan ìlẹ̀kùn, wí pé, Olúwa, Olúwa, ṣí i fún wa! Òun ó sì dáhùn wí fún yín pé, Èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá Nígbà náà ni ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, Àwa ti jẹ, àwa sì ti mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní ìgboro ìlú Òun ó sì wí pé, Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpahínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Ábúráhámù, àti Ísáákì, àti Jákọ́bù, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde Wọn ó sì ti ilẹ̀ ìlà òòrùn, àti ìwọ̀-òòrùn wá, àti láti àríwá, àti gúsù wá, wọn ó sì jókòó ní ìjọba Ọlọ́run Sì wò ó, àwọn ẹni ẹ̀yìn ń bẹ tí yóò di ẹni iwájú, àwọn ẹni ìwájú ń bẹ tí yóò di ẹni ẹ̀yìn Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhín-ín yìí nítorí Hẹ́rọ́dù ń fẹ́ pa ọ́ Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, Kíyèsí i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lóní àti lọ́la, àti ní ijọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé Ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ má rìn lóní, àti lọ́la, àti ní ọ̀túnla kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ pé wòlíì yóò ṣègbé lẹ́yìn odi Jerúsálémù Jerúsálémù, Jerúsálémù, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́! Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro lóòtóọ́ ni mo sì wí fún yín, Ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa   Jésù Ní Ilé Farisí Kan Nígbà tí ó wọ ilé ọ̀kan nínú àwọn olórí Farisí lọ ní ọjọ́ ìsinmi láti jẹun, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí ó ní àsunkún ń bẹ níwájú rẹ̀ Jésù sì dáhùn ó wí fún àwọn amòfin àti àwọn Farisí pé, Ǹjẹ́ ó tọ́ láti múni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, tàbi kò tọ́ Wọ́n sì dákẹ́ Ó sì mú un, ó sì mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, Ta ni nínú yín tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù rẹ̀ yóò bọ́ sínú ihò, tí kì yóò sì fà á sókè lójúkan náà ní ọjọ́ ìsinmi Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá ó sì wí fún wọn pé Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ wá sí ibi ìyàwó, má ṣe jókòó ní ipò ọlá kí ó má ba à jẹ́ pé, a ó pe ẹni tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ àti òun bá dé, a sì wí fún ọ pé, Fún ọkùnrin yìí ní àyè! Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá pè ọ́, lọ kí o sì jókòó ní ipò ẹ̀yìn nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, kí ó lè wí fún ọ pé, Ọ̀rẹ́, bọ́ sókè! Nígbà náà ni ìwọ ó ní ìyìn lójú àwọn tí ó bá ọ jókòó t'oúnjẹ Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ni a ó sì gbé ga Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, Nígbà tí ìwọ bá se àṣè ọ̀sán má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládúgbò rẹ̀ nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkù àrùn, àwọn amúkún-ún, àti àwọn afọ́jú Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún nítori wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòótọ́ Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jésù pé, Alábúkùn ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ ase ní ìjọba Ọlọ́run! Jésù dá a lóhùn pé, Ọkùnrin kan se àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀ Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, Ẹ wá nítorí ohun gbogbo ṣe tán! Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ ní ohùn kan láti ṣe àwáwí Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi Èkejì sì wí pé, Mo ra màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi Ẹ̀kẹ́ta sì wí pé, Mo sẹ̀sẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀ Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpòpò ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúkùn-ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, àyè sì ń bẹ síbẹ̀ Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún Nítorí mo wí fún yín, Ẹnìkẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́ wò nínú àsè ńlá mi!  Àwọn ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ń bá a lọ ó sì yípadà, ó sì wí fún wọn pé, Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kóríra bàbá rẹ̀, àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi Nítorí tani nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jòkòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀ Kí ó má baà jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà Wí pé, Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀ Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbàarún-ún pàdégun ẹni tí ń mú ẹgbàawàá bọ̀ wá ko òun lójú Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí onítọ̀hún bá sì wà ní òkèrè, òun a rán ikọ̀ sí i, a sì bẹ̀rẹ̀ àdéhùn àlààáfíà Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó ṣe nínú yín, tí kò kọ ohun gbogbo tí ó ní sílẹ̀, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi Iyọ̀ dára ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu, kínni a ó fi mú un dùn Kò yẹ fún ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ fún ààtàn bí kò ṣe pé kí a kó o dànù Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́ Òwe Àgùntàn Tó Sọnu Gbogbo àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ Àti àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé ń kùn pé, Ọkùnrin yìí ń gba ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun Ó sì pa òwe yìí fún wọn, pé, Ọkùnrin wo ni nínú yín, tí ó ní ọgọ̀rún-ún àgùntàn, bí ó bá sọ ọ̀kan nù nínú wọn, tí kì yóò sì tọ ipaṣẹ̀ èyí tí ó nù lọ, títí yóò fi rí i Nígbà tí ó bá sì rí i tán, yóò gbé e lé èjìká rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀ Nígbà tí ó bá sì dé ilé yóò pe àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóò sì wí fún wọn pé, Ẹ bá mí yọ̀ nítorí tí mo ti rí àgùntàn mi tí ó nù Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yóò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà, ju lórí olóòótọ́ mọ́kàndínlọ́gọ́rún-ún lọ, tí kò nílò ìrònúpìwàdà Tàbí obìnrin wo ni ó ní fàdákà mẹ́wàá bí ó bá sọ ọ̀kan nù, tí kì yóò tan fìtílà, kí ó fi gbá ilé, kí ó sì wá a gidigidi títí yóò fi rí i Nígbà tí ó sì rí i, ó pe àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, ó wí pé, Ẹ bá mi yọ̀ nítorí mo rí fàdákà tí mo ti sọnù Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ń bẹ níwájú àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run lórí ẹlẹ́sẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà Ó sì wí pé ọkùnrin kan ní ọmọ méjì Èyí àbúrò nínú wọn wí fún baba rẹ̀ pé, Baba, fún mi ní ìní tí ó kàn mí Ó sì pín ohun ìní rẹ̀ fún wọn Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní Ó sì lọ, ó da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ọlọ́tọ̀ kan ní ilẹ̀ náà òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ láti tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀ Ayọ̀ ni ìbá fi jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ ní àjẹyó ẹnikẹ́ni kò sì fifún un Ṣùgbọ́n nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní, Àwọn alágbàṣe baba mí mélòómélòó ni ó ní oúnjẹ àjẹyó, àti àjẹtì, èmi sì ń kú fún ebi níhìnín Èmi ó dìde, èmi ó sì tọ bàbá mi lọ, èmi ó sì wí fún un pé Bàbá, èmí ti dẹ́sẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ Èmi kò sì yẹ, ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́ fi mí ṣe ọ̀kan nínú àwọn alágbàṣe rẹ Ó sì dìde, ó sì tọ baba rẹ̀ lọ Ṣùgbọ́n nígbà tí ó sì wà ní òkèrè, baba rẹ̀ rí i, àánú ṣe é, ó sì súré, ó rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu Ọmọ náà sì wí fún un pé, Baba, èmi ti dẹ́sẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ, èmi kò yẹ ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́! Ṣùgbọ́n Baba náà wí fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Ẹ mú ààyò aṣọ wá kánkán, kí ẹ sì fi wọ̀ ọ́ ẹ sì fi òrùka bọ̀ ọ́ lọ́wọ́, àti bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ̀ Ẹ sì mú ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa wá, kí ẹ sì pa á kí a máa ṣe àríyá Nítorí ọmọ mi yìí ti kú, ó sì tún yè ó ti nù, a sì rí i Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í se àríyá Ṣùgbọ́n ọmọ rẹ̀ èyí ẹ̀gbọ́n ti wà ní oko bí ó sì ti ń bọ̀, tí ó súnmọ́ etí ilé, ó gbọ́ orin òun ijó Ó sì pe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn, ó béèrè, kíni a mọ nǹkan wọ̀nyí sí Ó sì wí fún un pé, Àbúrò rẹ dé, baba rẹ sì pa ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa, nítorí tí ó rí i padà ní àlààáfíà àti ní ìlera Ó sì bínú, ó sì kọ̀ láti wọlé bàbá rẹ̀ sì jáde, ó sì wá í sìpẹ̀ fún un Ó sì dáhùn ó wí fún bàbá rẹ̀ pé, Wòó, láti ọdún mélòó wọ̀nyí ni èmi ti ń sìn ọ́, èmi kò sì rú òfin rẹ rí ìwọ kò sì tí ì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi, láti fi bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe àríyá Ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tí ó fi panṣágà ru ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, ìwọ sì ti pa ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa fún un Ó sì wí fún un pé, Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ ń bẹ lọ́dọ̀ mi, ohun gbogbo tí mo sì ní, tìrẹ ni Ó yẹ kí a ṣe àríyá kí a sì yọ̀ nítorí àbúrò rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè ó ti nù, a sì rí i   Òwe Ọlọ́gbọ́n Òṣìṣẹ́ Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun-ìní rẹ̀ ṣòfò Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mọ́ Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, Èwo ni èmi ó ṣe Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi èmi kò lè walẹ̀ láti sàgbẹ̀ ojú ń tì mí Mo mọ èyí tí èmi yóò se, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi isẹ́ ìríjú, kí wọn kí ó le gbà mí sínú ilé wọn Ó sì pe àwọn ajigbèsè olúwa rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún èkínní pé, Èló ni ìwọ jẹ olúwa mi Ó sì wí pé, Ọgọ́rùn-ún Òṣùwọ̀n òróró Ó sì wí fún un pé, Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, Èló ni ìwọ́ jẹ Òun sì wí pé, Ọgọ́rùnún òsùwọ̀n àlìkámà Ó sì wí fún un pé, Mú ìwé rẹ, kí o sì kọ ọgọ́rin Olúwa rẹ̀ sì yin aláìṣòótọ́ ìríjú náà, nítorí tí ó fi ọgbọ́n ṣe é àwọn ọmọ ayé yìí sáà gbọ́n ní Ìran wọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ Èmi sì wí fún yín, ẹ fi mámónì àìṣòótọ́ yan ọ̀rẹ́ fún ara yín pé, nígbà tí yóò bá yẹ, kí wọn kí ó le gbà yín sí ibùjókòó wọn títí ayé Ẹni tí ó bá ṣe olóòótọ́ ní ohun kínkinní, ó ṣe olóòótọ́ ní púpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí ó bá sì ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun kínkinní, ó ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun púpọ̀ pẹ̀lú Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò bá ti jẹ́ olóòótọ́ ní mámónì àìṣòótọ́, tani yóò fi ọ̀rọ̀ tòótọ́ ṣú yín Bí ẹ̀yin kò bá sì ti jẹ́ olóòtítọ́ ní ohun tí í se ti ẹlòmíràn, tani yóò fún yín ní ohun tí í se ti ẹ̀yin tìkara yín Kò sí ìránṣẹ́ kan tí ó le sin olúwa méjì àyàfi kí ó kórìíra ọ̀kan, yóò sì fẹ́ èkejì tàbí yóò fi ara mọ́ ọ̀kan yóò sì yan èkejì ní ìpọ̀sì Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run pẹ̀lú mámónì Àwọn Farisí, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ sùtì sí i Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ̀yin ni àwọn tí ń dáre fún ara yín níwájú ènìyàn ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ ọkàn yín nítorí èyí tí a gbé níyìn lọ́dọ̀ ènìyàn, ìríra ni níwájú Ọlọ́run Òfin àti àwọn wòlíì ń bẹ títí di ìgbà Jòhánù Láti ìgbà náà wá ni a ti ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù sì ń fi ipá wọ inú rẹ̀ Ṣùgbọ́n ó rọrùn fún ọ̀run òun ayé láti kọjá lọ, ju kí sóńsó kan ti òfin kí ó yẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé òmíràn ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé, ẹni tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ asọ elésèé àlùkò àti asọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójóojúmọ́ Alágbe kan sì wà tí à ń pè ní Lásárù, tí wọ́n máa ń gbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fún ooju, Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn ańgẹ́lì gbé e lọ sí oókan-àyà Ábúráhámù ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín Ní ipò-òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìṣẹ́ oró, ó sì rí Ábúráhámù ní òkèrè, àti Lásárù ní oókan-àyà rẹ̀ Ó sì ké, ó wí pé, Baba Ábúráhámù, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lásárù, kí ó tẹ oríka rẹ̀ bọmi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí Ṣùgbọ́n Ábúráhámù wí pé, Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lásárù ohun búburú ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má baa le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá Ó sì wí pé, Ǹjẹ́ mo bẹ̀ ọ́, baba, kí ìwọ kí ó rán an lọ sí ilé baba mi Nítorí mo ní arákùnrin márùnún kí ó lè rò fún wọn kí àwọn kí ó má baa wá sí ibi oró yìí pẹ̀lú Ábúráhámù sì wí fún un pé, Wọ́n ní Mósè àti àwọn wòlíì kí wọn kí ó gbọ́ ti wọn Ó sì wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, Ábúráhámù baba ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ti inú òkú tọ̀ wọ́n lọ, wọn ó ronúpìwàdà Ó sì wí fún un pé, Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mósè àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde   Ẹ̀ṣẹ̀, Ìgbàgbọ́, Iṣẹ́ Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa dé ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipaṣẹ̀ rẹ̀ dé Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀ Ẹ máa kíyèsíra yín Bí arákùnrin rẹ bá sẹ̀, bá a wí bí ó bá sì ronúpìwàdà, dárí jìn ín Bí ó bá sì sẹ̀ ọ́ ní ẹ̀rìnméje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ẹ̀rẹ̀méje ní òòjọ́ pé, Mo ronúpìwàdà, dárí jìn ín Àwọn àpósítélì sì wí fún Olúwa pé, Bùsí ìgbàgbọ́ wa Olúwa sì wí pé, Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn músítadì, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi Músítádì yìí pé, Kí a fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú òkun, yóò sì gbọ́ ti yín Ṣùgbọ́n tani nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójú kan náà tí ó bá ti oko dé pé, Lọ í jòkòó láti jẹun Tí kì yóò kúkú wí fún un pé, Pèsè ohun tí èmi yóò jẹ, sì di àmùrè, kí ìwọ kí ó máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, títí èmi ó fi jẹ kí èmi ó sì mu tán lẹ́yìn náà ni ìwọ ó sì jẹ, tí ìwọ ó sì mu Òun ó ha máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nítorí ó ṣe ohun tí a pa láṣẹ fún un bí Èmi kò rò bẹ́ẹ̀ Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pàṣẹ fún yín tán, ẹ wí pé, Aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀ ni wá èyí tí í se iṣẹ́ wa láti ṣe, ní àwá ti ṣe   Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerúsálémù, ó kọjá láàrin Samaríà òun Gálílì Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè Wọ́n sì nahùn sókè, wí pé, Jésù, Olùkọ́, ṣàánú fún wa Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́ Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú Òun lára dá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀ ará Samáríà ni òun í ṣe Jésù sì dáhùn wí pé, Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́ Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí Ó sì wí fún un pé, Dìde, kí o sì máa lọ ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dá Nígbà tí àwọn Farisí bi í pé, nígbà wo ni ìjọba Ọlọ́run yóò dé, ó dá wọn lóhùn pé, Ìjọba Ọlọ́run kì í wá pẹ̀lú àmì Bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wí pé, Kíyèsí i níhìn ín! tàbí Kíyèsí i lọ́hùn ún ni! sáà wòó, ìjọba Ọlọ́run ń bẹ nínú yín Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí ẹ̀yin óò fẹ́ láti rí ọ̀kan nínú ọjọ́ ọmọ ènìyàn, ẹ̀yin kì yóò sì rí i Wọ́n sì wí fún yín pé, Wò ó níhìnín tàbí Wò ó lọ́hùn ún! Ẹ máa lọ, ẹ má se tẹ̀lé wọn Nítorí gẹ́gẹ́ bí mọ̀nàmọ́ná ti í kọ ní apákan lábẹ́ ọ̀run, tí sì í mọ́lẹ̀ ní apá kejì lábẹ́ ọ̀run bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ènìyàn yóò sì rí ní ọjọ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n kò lè sàìmá kọ́ jìyà ohun púpọ̀, kí a sì kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ ìran yìí Bí ó ti rí ní ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ ọmọ ènìyàn Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí ó fi di ọjọ́ ti Nóà wọ inú ọkọ̀ lọ, kíkún omi sì dé, ó sì run gbogbo wọn Bí ó sì ti rí ní ọjọ́ Lọ́ọ̀tì wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà tí Lọ́ọ̀tì jáde kúrò ní Ṣódómù, òjò iná àti súfúrù rọ̀ láti ọ̀run wá, ó sì run gbogbo wọn Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ náà tí ọmọ ènìyàn yóò farahàn Ní ọjọ́ náà, ẹni tí ó bá wà lórí ilé, tí ẹrù rẹ̀ sì ń bẹ ní ilẹ̀, kí ó má se sọ̀kalẹ̀ láti wá kó o ẹni tí ó bá sì wà ní oko, kí ó má ṣe padà sẹ́yìn Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá àti gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóò sọ ọ́ nù ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ nù yóò gbà á là Mo wí fún yín, ní òru ọjọ́ náà, ènìyàn méjì yóò wà lórí àkéte kan a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀ Ènìyàn méjì yóò sì máa lọ ọlọ pọ̀ a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀ Ènìyàn méjì yóò wà ní oko, a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀ Wọ́n sì dá a lóhùn, wọ́n bi í pé, Níbo, Olúwa Ó sì wí fún wọn pé, Níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ pẹ̀lú ni Igún ì kójọ pọ̀ sí Òwe Ìforítì Opò Ó sì pa òwe kan fún wọn nítorí èyí yìí pé, ó yẹ kí a má a gbàdúrà nígbà gbogbo, kí a má sì ṣàárẹ̀ Wí pé, Onídàájọ́ kan wà ní ìlú kan, tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ṣe ojúṣàáájú ènìyàn Opó kan sì wà ní ìlú náà, ó sì ń tọ̀ ọ́ wá, wí pé, Gbẹ̀san mi lára ọ̀ta mi! Lákọ̀ọ́kọ́ kò dá a lóhùn ṣùgbọ́n níkẹyìn ó wí nínú ara rẹ̀ pé, Bí èmi kò tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí èmi kò sì ṣe ojúṣàájú ènìyàn, Ṣùgbọ́n nítorí tí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, èmi ó gbẹ̀san rẹ̀, kí ó má baà fi wíwá rẹ̀ nígbákùúgbà dá mi lágara   Olúwa sì wí pé, Ẹ gbọ́ bí aláìṣòótọ́ onídàájọ́ ti wí! Ọlọ́run kì yóò ha sì gbẹ̀san àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, tí ń fi ọ̀sán àti òru kígbe pè é, tí ó sì mú sùúrù fún wọn Mo wí fún yín, yóò gbẹ̀san wọn kánkán! Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọmọ Ènìyàn bá dé yóò ha rí ìgbàgbọ́ ní ayé bí Ó sì pa òwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀le ara wọn pé, àwọn ni olódodo, tí wọ́n sì ń gan àwọn ẹlòmíràn Pé, Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹ́ḿpílì láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisí, èkejì sì jẹ́ agbowó òde Èyí Farisí dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì lọ́ṣẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀! Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè fi ọwọ́ lé wọn ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí Ṣùgbọ̀n Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí Ìjòyè kan sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wí pé, Olùkọ́ rere, kínni èmi ó ṣe tí èmi ó fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun Jésù wí fún un pé, Èéṣe tí ìwọ fi ń pè mí ní ẹni rere Ẹni rere kan kò sí bí kò ṣe ẹnìkan, èyí sì ni Ọlọ́run Ìwọ mọ̀ àwọn òfin, Má ṣe ṣe panṣágà, má ṣe pànìyàn, má ṣe jalè, má ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún bàbá àti ìyá rẹ   Ó sì wí pé, Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti pa mọ́ láti ìgbà èwe mi wá Nígbà tí Jésù sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀ lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn talákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra lọ́run sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀ Nígbà tí Jésù rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, ó wí pé, Yóò ti ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run! Nítorí ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run lọ Àwọn tí ó sì gbọ́ wí pé, Ǹjẹ́ tani ó ha lè là Ó sì wí pé, Ohun tí ó ṣòro lọ́dọ̀ ènìyàn kò ṣòro lọ́dọ̀ Ọlọ́run Pétérù sì wí pé, Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa silẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn! Ó sì wí fún wọn pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run, Tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun Nígbà náà ni ó pe àwọn méjìlá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, Sá wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerúsálémù, a ó sì mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, nítorí Ọmọ Ènìyàn Nítorí tí a ó fi lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́, a ó fi ṣe ẹlẹ́yà, a ó sì fi ṣe ẹ̀sín, a ó sì tutọ́ si i lára Wọn ó sì nà án, wọn ó sì pa á ní ijọ́ kẹ́ta yóò sì jíǹde Ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò sì yé wọn ọ̀rọ̀ yìí sì pamọ́ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ ohun tí a wí Bí ó ti súnmọ́ Jẹ́ríkò, afọ́jú kan jókòó lẹ́bá ọ̀nà ó ń ṣagbe Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó bèèrè pé, kíni a lè mọ èyí sí Wọ́n sì wí fún un pé, Jésù ti Násárẹ́tì ni ó ń kọjá lọ Ó sì kígbe pé, Jésù, ìwọ ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi! Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, Ìwọ Ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi! Jésù sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í, Wí pé, Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ Ó sì wí pé, Olúwa jẹ́ kí èmi ríran Jésù sì wí fún un pé, Ríran ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run Sákéù Agbowó Òde Jésù sì wọ Jẹ́ríkò lọ, ó sì ń kọjá láàrin rẹ̀ Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan wà tí a ń pè ní Sákéù, ó sì jẹ́ olórí agbowó òde kan, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀ Ó sì ń fẹ́ láti rí ẹni tí Jésù jẹ́ kò sì lè rí i, nítrorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti nítorí tí òun jẹ́ ènìyàn kúkúrú Ó sì súré ṣíwájú, ó gun orí igi síkámórè kan, kí ó bà lè rí i nítorí tí yóò kọjá lọ níhà ibẹ̀ Nígbà tí Jésù sì dé ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i, ó sì wí fún un pé, Sákéù! Yára, kí o sì sọ̀kalẹ̀ nítorí pé èmi yóò wọ ilé rẹ lóní Ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á Nígbà tí wọ́n sì rí i, gbogbo wọn ń kùn, wí pé, Ó lọ wọ̀ lọ́dọ̀ ọkùnrin tí í ṣe ẹlẹ́sẹ̀   Sákéù sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, Wòó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fifún talákà bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin! Jésù sì wí fún un pé, Lóní ni ìgbàlà wọ ilé yìí, níwọ̀n bí òun pẹ̀lú ti jẹ́ ọmọ Ábúráhámù Nítorí Ọmọ Ènìyàn dé láti wá àwọn tí ó nù kiri, àti láti gbà wọ́n là Nígbà tí wọ́n sì ń gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó sì tẹ̀ṣíwájú láti pa òwe kan, nítorí tí ó súnmọ Jerúsálémù, àti nítorí tí wọn ń rò pé, ìjọba Ọlọ́run yóò farahàn nísinsin yìí Ó sì wí pé, Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà Ó sì pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mínà mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ má a ṣòwò títí èmi ó fi dé! Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jọba lórí wa Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́-òwò wọn Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, Olúwa, owó mínà rẹ jèrè owó mínà mẹ́wá sí i Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, O ṣeun, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere! Nítorí tí ìwọ ṣe olóòótọ́ ní ohun kínkínní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá Èyí èkéjì sì wá, ó wí pé, Olúwa, owó mínà rẹ jèrè owó mínà márùnún Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, Ìwọ joyè ìlú márùnún! Òmíràn sì wá, ó wí pé, Olúwa, wòó owó mínà rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ-pélébé kan Nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn! Olúwa rẹ sì wí fún un pé, Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn Èé ha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowó pamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, Èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, Ẹ gba owó mínà náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó mínà mẹ́wàá Wọ́n sì wí fún un pé, Olúwa, ó ní owó mínà mẹ́wàá Mo wí fún yín pé, Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fifún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá mi wọ̀nyí, tí kò fẹ́ kí èmi jọba lórí wọn ẹ mú wọn wá ìhínyìí, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi!  Nígbà tí ó sì ti wí ǹkan wọ̀nyí tan, ó lọ ṣíwájú, ó ń gòkè lọ sí Jerúsálémù Ó sì ṣe, nígbà tí ó súnmọ́ Bẹtifágè àti Bétanì ní òkè tí a ń pè ní Ólífì, ó rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Wí pé, Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, Olúwa ń fẹ́ lò ó   Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà Wọ́n sì wí pé, Olúwa ń fẹ́ lò ó Wọ́n sì fà á tọ Jésù wá wọ́n sì tẹ́ ẹ wọ́n sì gbé Jésù kà á Bí ó sì ti ń lọ wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olófì, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí Wí pé, Olùbùkún ni Ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa! Àlààáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run! Àwọn kan nínú àwọn Farisí nínú àwùjọ náà sì wí fún un pé, Olùkọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, Mo wí fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó ṣíjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí, Ó ń wí pé, Ìbáṣepé ìwọ mọ̀, lóní yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí àlààáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ Ó sì wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde Ó sì wí fún wọn pé, A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò olè Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹ́ḿpìlì, Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á run Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀ Ìbí Jésù Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ Késárì Ògọ́sítù jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ìjọba Rosínú ìwé Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀ Jóṣéfù pẹ̀lú sì gòkè láti Násárẹ́tì ìlú Gálílì, sí ìlú Dáfídì ní Jùdéà, tí à ń pè ní Bétílẹ́hẹ́mù nítorí ti ìran àti ìdílé Dáfídì ní í ṣe, Láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Màríà aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ tí tó bi Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun óò bí Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran nítorí tí àyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò Àwọn olùsọ́-àgùntàn ńbẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń sọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé Ańgẹ́lì Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi Ańgẹ́lì náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù sá wò ó, mo mú ìyìn rere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónì-ín ní ìlú Dáfídì, tí í ṣe Kírísítì Olúwa Èyí ni yóò sì ṣe àmì fún yín ẹ̀yin yóò rí ọmọ-ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ Ańgẹ́lì náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé, Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run, Àti ní ayé àlààáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn ańgẹ́lì náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn Olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, Ẹ jẹ́ kí á lọ tàrà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀ jẹ, tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀ fún wa Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Màríà àti Jósẹ́fù, àti ọmọ-ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá Ṣùgbọ́n Màríà pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀ Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn Nígbà tí ijọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ańgẹ́lì náà wá kí á tó lóyún rẹ̀ nínú Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Màríà sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mósè, Josefu àti Màríà gbé Jésù wá sí Jerúsálémù láti fi í fún Olúwa , àti láti rúbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa àdàbà méjì tàbí ẹyẹlẹ́ méjì Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan wà ní Jerúsálémù, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣíméónì ọkùnrin náà sì ṣe olóòótọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Ísírẹ́lì Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí kírísítì Olúwa Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹ́ḿpìlì nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé ọmọ náà Jésù wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin, Nígbà náà ni Símọ́nì gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní Olúwa alágbára, nígbàyí ni o tó jọ̀wọ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ, Ní àlààáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ rẹ Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná, Tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo Ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà, Àti ògo Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀ Ẹnu sì ya Jóṣéfù àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí Síméónì sì súre fún wọn, ó sì wí fún Màríà ìyá rẹ̀ pé Kíyèsí i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Ísírẹ́lì àti fún àmì tí a ń sọ̀rọ̀ òdì sí kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn Ẹnìkan sì ń bẹ, Ánà wòlíì, ọmọbìnrin Fánúénì, ní ẹ̀yà Ásérì ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúndíá rẹ̀ wá Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹ́ḿpílì, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn-án àti lóru Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerúsálémù Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Gálílì, sí Násárẹ́tì ìlú wọn Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀ Àwọn òbi rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerúsálémù ní ọdọọdún sí Àjọ-ìrékọjá Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerúsálémù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jésù dúró lẹ́yìn ní Jerúsálémù Jóṣéfù àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀ Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerúsálémù, wọ́n ń wá a kiri Ó sì ṣe, lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹ́ḿpílì ó jòkòó ní àárin àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ ti wọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀ Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n ìyá rẹ̀ sì bi í pé, Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀ Sá wò ó, bàbá rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbìnújẹ́ wá ọ kiri Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri, ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi Ọ̀rọ̀ tí sọ kò sì yé wọn Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Násárétì, sì fi ara balẹ̀ fún wọn ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀ Jésù sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn Wọ́n Bèèrè Nípa Àṣẹ Jésù Ní ijọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹ́ḿpìlì tí ó sì ń wàásù ìyìn rere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn alàgbà dìde sí i Wọ́n sì wí fún un pé, Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe ǹkan wọ̀nyí Tàbí tani ó fún ọ ní àṣẹ yìí Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan ẹ sì fi ìdáhùn fún mi Bamitísímù ti Jòhánù, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn Wọ́n sì bá ara wọn gbérò pé, Bí àwa bá wí pé, Láti ọ̀run wá ni, òun ó wí pé, Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́ Ṣùgbọ́n bí àwa bá sì wí pé, Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, gbogbo ènìyàn ni yóò sọ wá ní òkúta, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé, wòlíì ni Jòhánù Wọ́n sì dáhùn wí pé, Wọn kò mọ̀ ibi tí ó ti wá Jésù sì wí fún wọn pé, Ǹjẹ́ èmi kì yóò wí fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùsọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́ Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùsọ́gbà náà kí wọn lè fún un nínú èṣo ọgbà àjàrà náà ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo Ó sì tún rán ọmọ-ọ̀dọ̀ míràn wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ níyà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo Ó sì tún rán ẹ̀kẹ́ta wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, Èwo ni èmi ó ṣe Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn ó ṣojúsájú fún un Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbérò pé, Èyí ni àrólé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tìí jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á Ǹjẹ́ kínni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, Kí a má ri I! Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé  Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, Òun náà ni ó di pàtàkì igun kilé Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́ ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá subú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn Wọ́n sì ń sọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn amí tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtọ́ ènìyàn, kí wọn baà lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn baà lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́ Wọ́n sì bí i, pé, Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣojúsájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lótítọ́ Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó-òde fún Késárì, tàbí kò tọ́ Ṣùgbọ́n ó kíyèsí àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ fi owó-idẹ kan hàn mí Àwòrán àti àkọlé ti tani ó wà níbẹ̀ Wọ́n sì dá a lóhùn pé, Ti Késárì ni Ó sì wí fún wọn pé, Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Késárì fún Késárì, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́ Àwọn Ṣadusí kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí wọ́n sì bi í, Wí pé, Olùkọ́, Mósè kọ̀wé fún wa pé Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀ Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ Èkejì sì ṣú u lópó òun sì kú ní àìlọ́mọ Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya tìtani yóò ha ṣe nínú wọn Nítorí àwọn méjèèje ni ó sáà ni ín ní aya Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún-ni Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún-ni Nítorí wọn kò lè kú mọ́ nítorí tí wọn bá àwọn áńgẹ́lì dọ́gba àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mósè tìkararẹ̀ sì ti fihàn ní ìgbẹ́, nígbà tí ó pe Olúwa ni Ọlọ́run Ábúráhámù, àti Ọlọ́run Ísáákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè nítorí gbogbo wọn wà láàyè fún un Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, Olùkọ́ ìwọ wí rere! Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́ Ó sì wí fún wọn pé, Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, Ọmọ Dáfídì ni Kírísítì Dáfídì tìkárarẹ̀ sì wí nínú ìwé Psalmu pé  JÈHÓFÀ wí fún Olúwa mi pé Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi Títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ   Ǹjẹ́ bí Dáfídì bá pè é ní Olúwa Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀ Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé, Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn ní aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú sínágọ́gù, àti ipò ọlá ní ibi àsè Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù Oore Opó Nígbà tí ó sì gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àpótí ìṣúra Ó sì rí talákà opó kan pẹ̀lú, ó ń sọ owó-idẹ wẹ́wẹ́ méjì síbẹ̀ Ó sì wí pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, tálákà opó yìí fi sí i ju gbogbo wọn lọ Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí fi sínú ẹ̀bùn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní wọn ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ní sínú rẹ̀ Bí àwọn kan sì ti ń sọ̀rọ̀ ti tẹ́ḿpílì, bí a ti fi òkúta dáradára àti ẹ̀bùn ṣe é ní ọ̀ṣọ́, ó ní, Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀ Wọ́n sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, Olùkọ́, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò rí bẹ́ẹ̀ Àti àmì kíní yóò wà, nígbà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ Ó sì wí pé, Ẹ máa kíyèsára, kí a má báà mú yín sìnà nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, tí yóò máa wí pé, Èmi ní Kírísítì náà àkókò náà sì kù sí dẹ̀dẹ̀ Ẹ má ṣe tọ̀ wọ́n lẹ́yìn Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá gbúròó ogun àti ìdágìrì, ẹ má ṣe fòyà nítorí nǹkan wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe lójúkan náà Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba Ilẹ̀ríri ilẹ̀ ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn ohun ẹ̀rù, àti àmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí sínágọ́gù, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi Yóò sì padà di ẹ̀rí fún yín Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ lọ́kàn yín pé ẹ yóò ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀ré on ó sì mú kì a pa nínú yín A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi Ṣùgbọ́n irun orí yín kan kì yóò ṣègbé Nínú sùúrù yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerúsálémù ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀ Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdéà sá lọ sórí òkè àti àwọn tí ń bẹ láàrin rẹ̀ kí wọn jáde kúrò kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbéríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fí ọmú fún ọmọ mu ní ijọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dì wọ́n ní ìgbékùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo Jerúsálémù yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún Àmì yóò sì wà ní ọ̀run, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀ àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpáyà híhó òkun àti ìgbì-omi Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì Nígbà náà ni wọn ó sì rí ọmọ-ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú ìkùukù àwọ̀sánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀ Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, Ẹ kíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnrarayín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́rẹ́fẹ́ Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o sẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé Ǹjẹ́ kì ẹ máa sọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ baà lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn Lọ́sàn-án, a sì máa kọ́ni ní tẹ́ḿpílì lóru, a sì máa jáde lọ wọ̀ lórí òkè tí à ń pè ní òkè Ólífì Gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá ní tẹ́ḿpílì ní kùtùkùtù òwúrọ̀, láti gbọ́rọ̀ rẹ̀ Júdásì Gbà Láti Da Jésù Àjọ ọdún àkàrà àìwú tí à ń pè ní Ìrékọjá sì kù fẹ́rẹ́fẹ́ Àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà tí wọn ìbá gbà pa á nítorí tí wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn Sàtánì sì wọ inú Júdásì, tí à ń pè ní Isíkáríọ́tù, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbérò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́ Wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì bá a dá májẹ̀mu láti fún un ní owó Ó sì gbà ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo Ojọ́ àkàrà àìwú pé, nígbà tí wọ́n ní láti ṣe ìrúbọ ìrékọjá Ó sì rán Pétérù àti Jòhánù, wí pé, Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ Wọ́n sì wí fún un pé, Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀ Ó sì wí fún wọn pé, Kíyèsí i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru iṣà omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀, kí ẹ sì wí fún baálé ilé náà pé, Olùkọ́ wí fún ọ pé Níbo ni gbọ̀ngàn àpèjẹ náà gbé wà, níbi tí èmi ó gbé jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi Òun ó sì fi gbọ̀ngàn ńlá kan lókè hàn yín, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin pèsè sílẹ̀ Wọ́n sì lọ wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó tí sọ fún wọn wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀ Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn àpósítélì pẹ̀lú rẹ̀ Ó sì wí fún wọn pé, Tinú-tinú ni èmi fẹ́ fi bá yín jẹ ìrékọjá yìí, kí èmi tó jìyà Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò jẹ nínú rẹ̀ mọ́, títí a ó fi mú un ṣẹ ní ìjọba Ọlọ́run Ó sì gba aago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé, Gba èyí, kí ẹ sì pín in láàrin ara yín Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fifún wọn, ó wí pé, Ẹ̀yí ni ara mí tí a fifún yín ẹ má a ṣe èyí ní ìrántí mi Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú aago, ó wí pé, Aago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsí i, ọwọ́ ẹni tí yóò fi mí hàn wà pẹ̀lú mi lórí tábìlì Ọmọ Ènìyàn ń lọ nítòótọ́ bí a tí pinnu rẹ̀ ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí a gbé ti fi í hàn Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè láàrin ara wọn, tani nínú wọn tí yóò ṣe nǹkan yìí Ìjà kan sì ń bẹ láàrin wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí níńu wọn Ó sì wí fún wọn pé, Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí àbúrò ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́ Nítorí tani ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí óunjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́ Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrin yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi, Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá Olúwa sì wí pé, Símónì, Símónì, wò ó, Sàtánì fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí àlìkámà Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀ àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le Ó sì wí fún un pé, Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú Ó sì wí pé, Mo wí fún ọ, Pétérù, àkùkọ kì yóò kọ lónìí-ín tí ìwọ ó fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, ìwọ kò mọ̀ mí Ó sì wí fún wọn pé, Nígbà tí mo rán yín lọ láìní àpò-owó, àti àpò, àti bàtà, ọ̀dá ohun kan dá yín bí Wọ́n sì wí pé, Rárá! Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹni tí ó bá ní àpò owó kí ó mú un, àti àpò pẹ̀lú ẹni tí kò bá sì ní idà, kí ó ta aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi ra ìkan Nítorí mo wí fún yín pé, Èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ lára mi, A sì kà á mọ́ àwọn arúfin Nítorí àwọn ohun wọ̀nyí nípa ti èmi yóò ní ìmúṣẹ Wọ́n sì wí pé, Olúwa, sá wò ó, idà méjì ń bẹ níhín-ín yìí! Ó sì wí fún wọn pé, Ó tó Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè ólífì, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwọ̀ Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà Wí pé, Baba, bí ìwọ bá fẹ́, gba ago yìí lọ́wọ́ mi ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe Ańgẹ́lì kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀ Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá ó bá wọn, wọ́n ń sùn fún ìbànújẹ́ Ó sì wí fún wọn pé, Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹ́wò Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsí i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Júdásì, ìkan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jésù láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu Jesù sì wí fún un pé, Júdásì, ìwọ yóò ha fi ìfẹnukonu fi Ọmọ ènìyàn hàn Nígbà tí àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń wo bí nǹkan yóò ti jásí, wọ́n bi í pé, Olúwa kí àwá fi idà ṣá wọn Ọ̀kan nínú wọn sì fi idà ṣá ọmọ-ẹ̀yìn olórí àlùfáà, ó sì gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn ó wí pé, Ẹ fi í sílẹ̀ báyìí ná Ó sì fi ọwọ́ tọ́ ọ ní etí, ó sì wò ó sàn Jésù wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ḿpìlì, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá Nígbà tí èmi wà pẹ̀lú yín lójojúmọ́ ní tẹ́ḿpílì, ẹ̀yin kò na ọwọ́ mú mi ṣùgbọ́n àkókò ti yín ni èyí, àti agbára òkùnkùn Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà Ṣùgbọ́n Pétérù tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrin gbọ̀ngàn, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Pétérù jokòó láàrin wọn Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀ Ṣùgbọ́n, ó wí pé, Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n Kò pẹ́ lẹ̀yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé, Ọkùnrin yìí, Èmi kọ́ Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀ nítorí ará Gálílì ní í ṣe Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé, Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí! Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ! Olúwa sì yípadà, ó wo Pétérù Pétérù sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta Pétérù sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò Ó sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jésù, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, Sọ tẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́ Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí I, láti fi ṣe ẹlẹ́yà Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọ pọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé, Bí ìwọ́ bá jẹ́ Kírísítì náà Sọ fún wa! Ó sì wí fún wọn pé, Bí mo bá wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ Bí mo bá sì bi yín léèrè pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yóò dá mi lóhùn, Ṣùgbọ́n láti ìsinsinyìí lọ ni ọmọ-ènìyàn yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run Gbogbo wọn sì wí pé, Ìwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọ́run bí Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ̀yin wí pé, èmi ni Wọ́n sì wí pé, Ẹ̀rí wo ni àwa tún ń fẹ́ Àwa tìkarawa sáà ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀! Wọ́n Kan Jésù Mọ́ Àgbélèbú Gbogbo ìjọ ènìyàn sì dìde, wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Pílátù Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án, wí pé, Àwa rí ọkùnrin yìí ó ń yí orílẹ̀-èdè wa lọ́kàn padà, ó sì ń dá wọn lẹ́kun láti san owó-òde fún Késárì, ó ń wí pé, òun tìkara-òun ni Kírísítì ọba Pílátù sì bi í léèrè, wí pé, Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù Ó sì dá a lóhùn wí pé, Ìwọ wí i Pílátù sì wí fún àwọn Olórí àlùfáà àti fún ìjọ ènìyàn pé, Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ Ọkùnrin yìí Wọ́n sì túbọ̀ tẹnumọ́ ọn pé, Ó ń ru ènìyàn sókè, ó ń kọ́ni káàkiri gbogbo Jùdéà, ó bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì títí ó fi dé ìhínyìí! Nígbà tí Pílátù gbọ́ orúkọ Gálílì, ó béèrè bí ọkùnrin náà bá jẹ́ ará Gálílì Nígbà tí ó sì mọ̀ pé ará ilẹ̀ Hẹ́rọ́dù ni, ó rán an sí Hẹ́rọ́dù, ẹni tí òun tìkárarẹ̀ wà ní Jerúsálémù ní àkókò náà Nígbà tí Hẹ́rọ́dù, sì rí Jésù, ó yọ̀ gidigidi nítorí tí ó ti ń fẹ́ rí i pẹ ó sáà ti ń gbọ́ ìhìn púpọ̀ nítorí rẹ̀ ó sì ń retí láti rí i kí iṣẹ́ àmì díẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe Ó sì béèrè ọ̀rọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò da a lóhùn rárá Àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé dúró, wọ́n sì ń fí ẹ̀sùn kàn án gidigidi Àti Hẹ́rọ́dù pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì ń fi í ṣẹ̀sín, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ dáradára, ó sì rán an padà tọ Pílátù lọ Pílátù àti Hẹ́rọdù di ọ̀rẹ́ ara wọn ní ijọ́ náà nítorí látijọ́ ọ̀tá ara wọn ni wọ́n ti jẹ́ rí Pílátù sì pe àwọn olórí àlúfáà àti àwọn olórí àti àwọn ènìyàn jọ Ó sọ fún wọn pé, Ẹyin mú ọkùnrin yìí tọ̀ mí wá, bí ẹni tí ó ń yí àwọn ènìyàn ní ọkàn padà sì kíyèsí i, èmí wádìí ẹjọ́ rẹ̀ níwájú yín èmi kò sì rí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ ọkùnrin yìí, ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ẹ̀yin fi ẹ̀sùn rẹ̀ sùn Àti Hẹ́rọ́dù pẹ̀lú ó sá rán an padà tọ̀ wá wá sì kíyèsí i, ohun kan tí ó yẹ sí ikú ni a kò ṣe láti ọwọ́ rẹ̀ Ǹjẹ́ èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀ lọ Wọ́n sì kígbe sókè nígbà kan náà, pé, Mú ọkùnrin yìí kúrò, kí o sì dá Bárábà sílẹ̀ fún wa! Ẹni tí a sọ sínú túbú nítorí ọ̀tẹ̀ kan tí a ṣe ní ìlú, àti nítorí ìpànìyàn Pílátù sì tún bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó fẹ́ dá Jésù sílẹ̀ Ṣùgbọ́n wọ́n kígbe, wí pé, Kàn án mọ́ àgbélèbú, kàn án mọ àgbélèbú! Ó sì wí fún wọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, Èéṣe, búburú kínni ọkùnrin yìí ṣe Èmi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀ nítorí náà èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀ Wọ́n túbọ̀ tẹramọ́ igbe ńlá, wọ́n ń fẹ́ kí a kàn án mọ́ àgbélèbú, Ohùn tiwọn àti ti àwọn olórí àlùfáà borí tirẹ̀ Pílátù sí fi àṣẹ sí i pé, kí ó rí bí wọ́n ti ń fẹ́ Ó sì dá ẹni tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀ fún wọn, ẹni tí a tìtorí ọ̀tẹ̀ àti ìpànìyàn sọ sínú túbú ṣùgbọ́n ó fi Jésù lé wọn lọ́wọ́ Bí wọ́n sì ti ń fà á lọ, wọ́n mú ọkùnrin kan, Símónì ara Kírénè, tí ó ń ti ìgbéríko bọ̀, òun ni wọ́n sì gbé àgbélèbú náà lé, kí ó máa rù ú lọ tẹ̀lé Jésù Ìjọ ènìyàn púpọ̀ ni ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, àti àwọn obìnrin, tí ń pohùnréré ẹkún Ṣùgbọ̀n Jésù yíjú padà sí wọn, ó sì wí pé, Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálémù, ẹ má sọkún fún mi, ṣùgbọ́n ẹ sọkún fún ara yín, àti fún àwọn ọmọ yín Nítorí kíyèsí i, ọjọ́ ń bọ̀ ní èyí tí ẹ̀yin ó wí pé, Ìbùkún ni fún àgàn, àti fún inú tí kò bímọ rí, àti fún ọmú tí kò fúnni mu rí! Nígbà náà ni  wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kékèké pé, Bò wá mọ́lẹ̀! Nítorí bí wọn bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sára igi tútù, kínni a ó ṣe sára gbígbẹ Àwọn méjì mìíràn bákàn náà, àwọn arúfin, ni wọ́n sì fà lọ pẹ̀lú rẹ̀ láti pa Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélèbú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì Jésù sì wí pé, Baba, dáríjì wọ́n nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn Àwọn ènìyàn sì dúró ń wòran Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, Ó gba àwọn ẹlòmíràn là kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kírísítì, àyànfẹ́ Ọlọ́run Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un Wọ́n sì ń wí pé, Bí ìwọ́ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Gíríkì, àti ti Látínì, àti tí Hébérù ÈYÍ NI ỌBA ÀWỌN JÚÙ Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, Bí ìwọ bá ṣe Kírísítì, gba ara rẹ àti àwa là Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwá ṣe ni à ń jẹ ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan Ó sì wí pé, Jésù, rántí mi nígbà tí ìwọ́ bá dé ìjọba rẹ Jésù sì wí fún un pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónì-ín ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Párádísè! Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́ Òòrùn sì ṣóòkùn, aṣọ ìkéle ti tẹ́ḿpílì sì ya ní àárin méjì, Nígbà tí Jésù sì kígbe lóhùn rara, ó ní, Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé! Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ Nígbà tí balógun ọ̀rún rí ohun tí ó ṣe, ó yin Ọlọ́run lógo, wí pé, Dájúdájú olódodo ni ọkùnrin yìí! Gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ láti rí ìran yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọ́n lu ara wọn ní oókan àyà, wọ́n sì padà sí ilé Àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀, àti àwọn obìnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Gálílì wá, wọ́n dúró lókèrè, wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jóṣẹ́fù, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatíyà Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòótọ́ Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run Ọkùnrin yìí tọ Pílátù lọ, ó sì tọrọ òkú Jésù Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀ Àti àwọn obìnrin, tí wọ́n bá a ti Gálílì wá, tí wọ́n sì tẹ̀lé, wọ́n kíyèsí ibojì náà, àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀ sílẹ̀ Nígbà tí wọ́n sì padà, wọ́n pèsè ohun olóòórn dídùn, òróró ìkunra Wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí òfin Àjíǹde Náà Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀sẹ̀, àwọn obìnrin wá sí ibojì, wọ́n sì mú lọ́fíńdà ti wọ́n tí pèsè sílẹ̀ wá Òkúta ti yí kúrò ní ẹnu ibojì Nígbà tí wọ́n sì wọ inú rẹ̀, wọn kò rí òkú Jésù Olúwa Bí wọ́n ti dààmú kiri níhà ibẹ̀, kíyèsí i, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ dídán dúró tì wọ́n Nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí wọ́n sì dojúbolẹ̀, àwọn ańgẹ́lì náà bi wọ́n pé, Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láàrin àwọn òkú Kò sí níhínyìí, ṣùgbọ́n ó jíǹde ẹ rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Gálílì Pé, A ó fi ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélèbú, ní ijọ́ kẹ́ta yóò sì jíǹde   Wọ́n sì rántí ọ̀rọ̀ rẹ̀ Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù Màríà Magaléènì, àti Jóánnà, àti Màríà ìyá Jákọ́bù, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn sì ni àwọn tí ó ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn àpósítélì Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì dàbí ìsọkúsọ lójú wọn, wọn kò sì gbà wọ́n gbọ́ Nígbà náà ni Pétérù dìde, ó súré lọ sí ibojì nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnrarawọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe Sì kíyèsí i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ijọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Èmáúsì, tí ó jìnnà sí Jerúsálémù níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀ Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀ Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jésù tìkara rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n Ó sì bi wọ́n pé, Ọ̀rọ̀ kínni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kíléópà, sì dáhùn wí fún un pé, Àlejò sáà ni ìwọ ní Jerúsálémù, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí Ó sì bi wọ́n pé, Kí ni Wọ́n sì wí fún un pé, Ní ti Jésù ti Násárẹ́tì, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn, Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélèbú Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Ísírẹ́lì ní ìdè Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹ́ta tí nǹkan wọ̀nyí ti sẹlẹ̀ Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá dá wa níjì Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn ańgẹ́lì tí wọ́n wí pé, ó wà láàyè Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí ṣùgbọ́n òun tìkárarẹ̀ ni wọn kò rí Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́ Kò ha yẹ kí Kírísítì ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mósè àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀ Wọ́n sì súnmọ́ ìletò tí wọ́n ń lọ ó sì ṣe bí ẹni pé yóò lọ sí iwájú Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, Bá wa dúró nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fifún wọn Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n ó sì nù mọ́ wọn ní ojú Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa! Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerúsálémù, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn, Èmí wí pé, Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Símónì! Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mímọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà Bí wọ́n sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí Jésù tìkararẹ̀ dúró láàrin wọn, ó sì wí fún wọn pé, Àlààáfíà fún yín Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì díjì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan Ó sì wí fún wọn pé, Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀ Èé sì ti ṣe tí ìròkúrò fi ń sọ nínú ọkàn yín Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkarami ni! Ẹ dì mí mú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n Nígbà tí wọn kò sì tí ì gbàgbọ́ fún ayọ̀, àti fún ìyanu, ó wí fún wọn pé, Ẹ̀yin ní ohunkóhun jíjẹ níhín yìí Wọ́n sì fún un ní ẹja tí a fi oyin sè Ó sì gbà á, ó jẹ ẹ́ lójú wọn Ó sì wí fún wọn pé, Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé A ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mósè, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Sáàmù, nípasẹ̀ mi Nígbà náà ni ó ṣí wọn níyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn Ó sì wí fún wọn pé, Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé Kí Kírísítì jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ijọ́ kẹ́ta kúrò nínú òkú Àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀ èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálémù lọ Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí Sì kíyèsí i, mo rán ìlérí Baba mi sí yín ṣùgbọ́n ẹ jókòó ní ìlú Jerúsálémù, títí a ó fifi agbára wọ̀ yín, láti òkè ọ̀run wá Ó sì mú wọn jáde lọ títí wọ́n fẹ́rẹ̀ dé Bétanì, nígbà tí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn Ó sì ṣe, bí ó ti ń súre fún wọn, ó yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, a sì gbé e lọ sí ọ̀run Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì padà lọ sí Jerúsálémù pẹ̀lú ayọ̀ púpọ̀ Wọ́n sì wà ní tẹ́ḿpìlì nígbà gbogbo, wọ́n ń fi ìyìn, àti ìbùkún fún Ọlọ́run Àmín Jòhánù Onítẹ̀bọmi Tún Ọ̀nà Náà Ṣe Ní ọdún kẹẹ̀dógún ìjọba Tiberíù Késárì, nígbà tí Pontíù Pílátù jẹ́ Baálẹ̀ Jùdéà, tí Hẹ́ródù sì jẹ́ tẹ́tírákì Gálílì, Fílípì arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetírákì Ituréà àti ti Tirakonítì, Nísáníà sì jẹ́ Tétírákì Ábílénì, Tí Ánásì òun Káíáfà ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Jòhánù ọmọ Sakaráyà wá ní ijù Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ ìha Jọ́dánì, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ Bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Àìṣáyà pé, Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, Ẹ mú ipa-ọ̀nà rẹ̀ tọ́ Gbogbo ọ̀gbun ni a óò kún, Gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ̀bẹ̀rẹ̀ Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́, àti ọ̀nà gbọ́ngun-gbọ̀ngun ni a o sọ di dídán Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run   Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀ Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wí nínú ara yín pé, Àwá ní Ábúráhámù ní baba Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Ábúráhámù nínú òkúta wọ̀nyí Àti nísinsìnyí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a ké e lulẹ̀, a sì wọ́ ọ jù sínú iná Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, Kí ni kí àwa kí ó ha ṣe Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́ Àwọn ọmọ-ogun sì bèèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, Àti àwa, kíni àwa ó ṣe Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùneké sí ẹnikẹ́ni kí òwò ọ̀yà yín tó yín Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Jòhánù, bí òun ni Kírísítì bí òun kọ́ Jòhánù dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamtíìsì yín ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ńbọ̀, okùn bàtà ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ítú òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamtísì yín Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tótó, kí ó sì kó àlìkámà rẹ̀ sínú àká ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun Jòhánù lo oríìṣíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìhìnrere fún wọn Ṣùgbọ́n nígbà ti Jòhánù bú Hẹ́rọ́dù tetírakì, tí ó bá wí nítorí Hérọ́díà aya Fílípì arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Hẹ́ródù tí ṣe, Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ ní tí ó fi Jòhánù sínú túbú Nígbà tí a sì ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamtíìsì Jésù pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi Jésù tìkara rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ ọmọ Jósẹ́fù, tí í ṣe ọmọ Élì, Tí í ṣe ọmọ Mátatì, tí í ṣe ọmọ Léfì, tí í ṣe ọmọ Melíkì, tí í ṣe ọmọ Janà, tí í ṣe ọmọ Jóṣẹ́fù, Tí í ṣe ọmọ Matataì, tí í ṣe ọmọ Ámósì, tí í ṣe ọmọ Náúmù, tí í ṣe ọmọ Ésílì, tí í ṣe ọmọ Nágáì, Tí í ṣe ọmọ Máátì, tí í ṣe ọmọ Matatíà, tí í ṣe ọmọ Síméì, tí í ṣe ọmọ Jósẹ́fù, tí í ṣe ọmọ Jódà, Tí í ṣe ọmọ Jóánà, tí í ṣe ọmọ Résà, tí í ṣe ọmọ Sérúbábélì, tí í ṣe ọmọ Sítíélì, tí í ṣe ọmọ Nérì, Tí í ṣe ọmọ Melíkì, tí í ṣe ọmọ Ádì, tí í ṣe ọmọ Kòsámù, tí í ṣe ọmọ Élímadámù, tí í ṣe ọmọ Érì, Tí í ṣe ọmọ Jósúà, tí í ṣe ọmọ Élíásérì, tí í ṣe ọmọ Jórímù, tí í ṣe Màtátì, tí í ṣe ọmọ Léfì, Tí í ṣe ọmọ Síméónì, tí í ṣe ọmọ Júdà, tí í ṣe ọmọ Jóséfù, tí í ṣe ọmọ Jónámù, tí í ṣe ọmọ Élíákímù, Tí í ṣe ọmọ Méléà, tí í ṣe ọmọ Méná, tí í ṣe ọmọ Mátatà, tí í ṣe ọmọ Nátanì, tí í ṣe ọmọ Dáfídì, Tí í ṣe ọmọ Jésè, tí í ṣe ọmọ Óbédì, tí í ṣe ọmọ Bóásì, tí í ṣe ọmọ Sólómónì, tí í ṣe ọmọ Náásónì, Tí í ṣe ọmọ Ámínádábù, tí íṣe ọmọ Rámù, tí í ṣe ọmọ Ésírónì, tí í ṣe ọmọ Fárésì, tí í ṣe ọmọ Júdà Tí í ṣe ọmọ Jákọ́bù, tí í ṣe ọmọ Ísáákì, tí í ṣe ọmọ Ábúráhámù, tí í ṣe ọmọ Térà, tí í ṣe ọmọ Náhórì, Tí í ṣe ọmọ Sárúgù, tí í ṣe ọmọ Rágáù, tí í ṣe ọmọ Fálékì, tí í ṣe ọmọ Ébérì, tí í ṣe ọmọ Sélà Tí í ṣe ọmọ Kénánì, tí í ṣe ọmọ Árífásádì, tí í ṣe ọmọ Sémù, tí í ṣe ọmọ Nóà, tí í ṣe ọmọ Lámékì, Tí í ṣe ọmọ Mètúsélà, tí í ṣe ọmọ Énókù, tí í ṣe ọmọ Járédì, tí í ṣe ọmọ Máléléénì, tí í ṣe ọmọ Kénánì Tí í ṣe ọmọ Énósì, tí í ṣe ọmọ Sétì, tí í ṣe ọmọ Ádámù, tí í ṣe ọmọ Ọlọ́run Ìdánwò Jésù Jésù sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jọ́dánì wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ Èṣù Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á Èṣù sì wí fún un pé, Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà Jésù sì dáhùn, ó wí fún un pé, A ti kọ̀wé rẹ̀ pé Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípa àkàrà nìkan Lójú kan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀-ọba ayé hàn án Ó sì wí fún un pé, Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún nítorí á sá ti fi fún mi ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún Ǹjẹ́ bí ìwọ bá foríbalẹ̀ fún mi, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ Jésù sì dáhùn ó sì wí fún un pé, Kúrò lẹ́yìn mi, Sátánì, nítorí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, Ìwọ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ kí ó sì máa sìn   Èsu sì mú un lọ sí Jerúsálémù, ó sì gbé e lé ṣóńṣo tẹ́ḿpílì, ó sì wí fún un pé, Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé  Yóò pàṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ, láti máa ṣe ìtọ́jú rẹ Àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè, kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta   Jésù sì dahùn ó wí fún un pé, A ti sọ pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò   Nígbà tí Èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ di sáà kan Jésù sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Gálílì òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká Ó sì ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá Ó sì wá sí Násárẹ́tì, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú sínágọ́gù lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé A sì fi ìwé wòlíì Àìsáyà fún un Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi, Nítorí tí ó fi àmì òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòsì Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú, àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́, Láti kéde ọdún ojúrere Olúwa Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú sínágọ́gù sì tẹjúmọ́ ọn Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, Lónì-ín ìwé-Mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, Ọmọ Jósẹ́fù kọ́ yìí Jésù sì wí fún wọn pé, Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwé yìí sí mi pé, Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwá gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapanáúmù, ṣe é níhín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ   Ó sì wí pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́ gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀ Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó pípọ̀ ni ó wà ní Ísírẹ́lì nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Èlíjà sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sáréfátì, ìlú kan ní Ṣídónì Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní Ísírẹ́lì nígbà wòlíì Èlíṣà kò sì sí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe Námánì ará Síríà Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú sínágọ́gù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú wọ́n ru ṣùṣù, Wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè taari rẹ̀ ní ògèdèǹgbé Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrin wọn, ó bá tirẹ̀ lọ Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kápánáúmù, ìlú kan ní Gálílì, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nítorí tàsẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ Ọkùnrin kan sì wà nínú Sínágọ́gù, ẹni tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó kígbe ní ohùn rara, Ó ní, kíní ṣe tàwa tìrẹ, Jésù ará Násárẹ́tì Ìwọ́ wá láti pa wá run bí Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run Jésù sì bá a wí gidigidi, ó ní, Pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì jáde lára rẹ̀ Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà sì gbé e ṣánlẹ̀ ní àwùjọ, ó jáde kúrò lára rẹ̀, kò sì pa á lára Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, ẹ̀kọ́ kínni èyi Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò Òkìkí rẹ̀ sì kàn níbi gbogbo ní agbégbé ilẹ̀ náà yíká Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú sínágọ́gù, ó sì wọ̀ ilé Símónì lọ ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Símónì gúnlẹ̀ wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀ Ó sì sunmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí ibà sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ó sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn Nígbà tí oòrun sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn mú àwọn aláìsàn tó ní onírúurú àìsàn wá sọ́dọ̀ Jésù ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run! Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn nítorí tí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kírísítì náà Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Jésù sì jáde lọ ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ Ìjọ ènìyàn sì ń wá a kiri, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì dá a dúró, nítorí kí ó má baà lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé, Èmi kò lè ṣàì má wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú nítorí náà ni a sá ṣe rán mi Ó sì ń wàásù nínú sínágọ́gù ti Jùdíà Ìpè Awọn Omọ Ẹ̀yìn Àkọ́kọ́ Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn ṣún mọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Gẹ́nẹ́sárétì, Ó rí ọkọ̀ méjì tọ́ wá létí adágún èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn Ó sì wọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, tí í ṣe ti Símónì, ó sì bẹ̀ ẹ́ kí ó tìí sí ẹ̀yìn díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ Ó sì jókòó, ó sì ń kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ náà Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ í sọ, ó wí fún Símónì pé, Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀ Símónì sì dáhùn ó sì wí fún un pé, Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀ Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja àwọ̀n wọn sì ya Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà ní ọkọ̀ kéjì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́ Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì Nígbà tí Símónì Pétérù sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bá eékún Jésù, ó wí pé, Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa nítorí ẹlẹ́sẹ̀ ni mí Ẹnu sì yàá wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó Bẹ́ẹ̀ ni Jákọ́bù àti Jòhánù àwọn ọmọ Sébédè, tí ń ṣe alábàákẹ́gbẹ́ Símónì Jésù sì wí fún Símónì pé, Má bẹ̀rù láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa sàwárí àwọn ẹlẹ́sẹ̀ Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ Ó sì ṣe, nígbà tí Jésù wọ ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà, kíyèsí i, ọkùnrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò nígbà tí ó rí Jésù, ó wólẹ̀, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mí di mímọ́ Jésù sì na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́! Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ Ó sì kìlọ̀ fún u pé, Kí ó má ṣe sọ fún ẹnìkan ṣùgbọ́n kí ó lọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí ó sì ta ọrẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mósè ti pàṣẹ fún ẹ̀rí sí wọn Ṣùgbọ́n òkìkí rẹ̀ ń kàn kálẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì jùmọ̀ pàdé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba dídá ara lọ́dọ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìlera wọn Ṣùgbọ́n ésù a máa yẹra kúrò, òun á sì máa dáwà láti gbàdúrà Ní ijọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisí àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Gálílì gbogbo, àti Jùdíà, àti Jerúsálémù wá agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá Sáà sì kíyèsí i, àwọn Ọkùnrin kan gbé ẹnikantí ó ní àrùn egba wà lórí àketè wọ́n ń wá ọ̀nà àti gbé e wọlé, àti láti tẹ́ ẹ ṣíwájú Jésù Nígbà tí wọn kò sì rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi gbé e wọlé nítorí ìjọ ènìyàn, wọ́n gbé e gun òkè àjà ilé lọ, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí àárín èrò ti òun ti àketè rẹ̀ níwájú Jésù Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé, Ọkùnrin yìí, a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́ Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí í gbérò wí pé, Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀ òdì Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo Jésù sì mọ ìrò inú wọn, ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, Èéṣe tí ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín Èwo ni ó yá jù láti wí pé, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, tàbí láti wí pé, Dìde kí ìwọ sì má a rìn Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ọmọ ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini… Ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, Mo wí fún ọ, dìde, sì gbé àketè rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé! Ó sì dìde lọ́gán níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n ń wí pé, Àwá rí ohun abàmì lónì-ín Lẹ́hìn èyí, Jésù jáde lọ, ó sì rí agbowó òde kan tí à ń pè ní Léfì ó jòkòó sí ibi tí ó ti ń gba owó òde, Jésù sì wí fún un pé Tẹ̀lé mi, Léfì sì fi ohun gbogbo sílẹ̀ ó sì ń tẹ̀lé e Léfì sì ṣe àṣè ńlá kan fún Jésù ní ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn mìíràn sì ń jẹun pẹ̀lú wọn Ṣùgbọ́n àwọn Farisí, àwọn olùkọ́ òfin tí ó jẹ́ ara wọn fi wọ́n hàn sí àwọn ọmọ ẹ̀hìn èéṣe tí ẹ̀yin fi ń jẹun tí ẹ sì ń mú pẹ́lú àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ Jésù dáhùn ó wí fún wọn pé Ẹni tí ara rẹ̀ le kò nílò oníṣègùm, bí kò ṣe ẹni tí ara rẹ̀ kò dá Èmí kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà Wọ́n wí fún un wí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù a máa gbàwẹ̀, wọn a sì máa gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí ṣùgbọ̀n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ a máa jẹ, wọn a sì máa mu pẹ̀lú Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, Ǹjẹ́ ó seé se kí àwọn àlejò ọkọ ìyàwó máa gbàwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ́lú wọn bí Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyìí ni wọn yóò gbàwẹ̀ Ó sì pa òwe yìí fún wọn wí pé Kò sí ẹni tó lè ya asọ tuntun kí ó sì rán mọ́, èyí tó ti gbó Tí ó ba ṣe èyí, yóò ba asọ tuntun jẹ́, èyí tí ó tuntun náà kì yóò ṣe dógba pẹ̀lú èyí tí ó ti gbó Àti wí pé, kò sí ẹni tí ó lè dá otí wáìnì sínú ògbólógbò awọ, tí ó bá ṣe èyí, wáìnì tuntun yóò fa awọ náà ya, wáìnì náà yóò dànù awo náà a sí Nítorí náà, ó tọ́ kí á da wáìnì tuntun sínú awọ tuntun Kò sì ẹni tí yóò fẹ́ láti mu wáìnì tuntun lẹ́yìn tí ó bá ti mu ogbólógbò tán, nítorí yóò wí pé èyí tí ó jẹ́ ògbólógbò dára jù Olúwa Ọjọ́ Ìsinmi Ní ọjọ́ ìsinmi kan, Jésù ń kọjá láàrin oko ọkà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń ya ìpẹ́ ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́ Àwọn kan nínú àwọn Farisí sì wí fún wọn pé, Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe èyí tí kò yẹ láti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi Jésù sì dá wọn lóhùn pé, Ẹ̀yin kò kà nípa ohun tí Dáfídì ṣe, nígbà tí ebi ń pa òun tìkárarẹ̀ àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ó ti wọ ilé Ọlọ́run lọ, tí ó sì mú àkàrà ìfihàn tí ó sì jẹ ẹ́, tí ó sì fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú tí kò yẹ fún un láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà níkan ṣoṣo Ó sì wí fún wọn pé, Ọmọ ènìyàn ni Olúwa ọjọ́ ìsinmi Ní ọjọ́ ìsinmi mìíràn, ó wọ inú sínágọ́gù lọ, ó sì ń kọ́ni, ọkùnrin kan sì ń bẹ níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún rọ Àti àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí ń ṣọ́ ọ, bí yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi kí wọn lè rí ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kàn án Ṣùgbọ́n ó mọ ìrò inú wọn, ó sì wí fún ọkùnrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, Dìde, kí o sì dúró láàrin Ó sì dìde dúró Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, Èmi bi yín léèrè, Ó ha tọ́ láti máa ṣe rere ni ọjọ́ ìsinmi, tàbí láti máa ṣe búburú Láti gba ọkàn là, tàbí láti pa á run Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká, ó wí fún ọkùnrin náà pé, Na ọwọ́ rẹ Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí èkejì Wọ́n sì kún fún ìbínú gbígbóná wọ́n sì bá ara wọn rò ohun tí àwọn ìbá ṣe sí Jésù Ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ wọnnì, Jésù lọ sí orí òkè lọ gbàdúrà, ó sì fi gbogbo òru náà gbàdúrà sí Ọlọ́run Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nínú wọn ni ó sì yan méjìlá, tí ó sì sọ ní àpósítélì Símónì àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀, Jákọ́bù àti Jòhánù, Fílípì àti Batolóméù Mátíù àti Tọ́másì, Jákọ́bù ọmọ Álíféù, àti Símónì tí a ń pè ní Ṣélótè, Àti Júdà arákùnrin Jákọ́bù, àti Júdásì Ísíkáríótù tí ó di ọ̀dàlẹ̀ Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀, ó sì dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú ọpọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn, láti gbogbo Jùdéà, àti Jerúsálémù, àti agbègbè Tírè àti Ṣídónì, tí wọ́n wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìmúláradá kúrò nínú àrùn wọn Àti àwọn tí ara wọn kún fún ẹ̀mí àìmọ́ ni ó sì mú láradá Gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń fẹ́ láti fọwọ́ kàn án, nítorí tí àṣẹ ń jáde lára rẹ̀, ó sì mú gbogbo wọn láradá Nígbà tí ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ èyìn rẹ̀, ó ní Alábùkún fún ni ẹ̀yin òtòsì, nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọ́run Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ebi ń pa nísinsin yìí nítorí tí ẹ ó yòó Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ń sọkún nísinsin yìí nítorí tí ẹ̀yin ó rẹ́rìn-ín Alábùkún fún ni ẹ̀yin, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kóríra yín, tí wọ́n bá yà yín kúrò nínú ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n bá gàn yín, tí wọ́n bá ta orúkọ yín nù bí ohun búburú, nítorí ọmọ ènìyàn Kí ẹ̀yin yọ̀ ní ọjọ́ náà, kí ẹ̀yin sì fò sókè fún ayọ̀, nítorí tí ẹ̀yin ti gba ìtùnú yín ná Ègbé ni fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀ nítorí ẹ ti gba ìtùnú yín Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ó yó, nítorí ebi yóò pa yín, Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń rẹ́rìn-ín nísinsin yìí, nítorí tí ẹ̀yin ó ṣọ̀fọ̀, ẹ̀yin ó sì sọkún Ègbé ni fún yín, nígbà tí gbogbo ènìyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín ní rere, nítorí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn èké wòlíì Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń gbọ́ mi Ẹ fẹ́ àwọn ọ̀ta yín, ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín Súre fún àwọn tí ń fi yín ré, sì gbàdúrà fún àwọn tí ń kẹ́gàn yín Ẹni tí ó bá sì lù ọ́ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan, pa èkejì dà sí i pẹ̀lú àti ẹni tí ó gba agbádá rẹ, má ṣe dá a dúró láti gba ẹ̀wù rẹ pẹ̀lú Sì fifún gbogbo ẹni tí ó tọrọ lọ́dọ̀ rẹ lọ́dọ̀ ẹni tí ó sì kó ọ lẹ́rù, má sì ṣe padà bèèrè Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti fẹ́ kí ènìyàn ṣe sí yín, kí ẹ̀yin sì ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn pẹ̀lú Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin bá fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ yín, ọpẹ́ kíni ẹ̀yin ní Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú ń fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ wọn Bí ẹ̀yin sì ṣoore fún àwọn tí ó ṣoore fún yín, ọpẹ́ kíni ẹ̀yin ní Àwọn ẹlẹ́sẹ̀ pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ Bí ẹ̀yin bá wín fún ẹni tí ẹ̀yin ń reti láti rí gbà padà, ọpẹ́ kínni ẹ̀yin ní Àwọn ẹlẹ́sẹ̀ pẹ̀lú ń yá ẹlẹ́sẹ̀, kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀ta yín kí ẹ̀yin sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ ọ̀gá ògo ni a ó sì máa pè yín nítorí tí ó ṣeun fún aláìmoore àti fún ẹni búburú Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́ ẹ má ṣe dáni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín Ẹ fifún ni, a ó sì fifún yín òṣùnwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ̀n fún àyà yín nítorí òṣùnwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ̀n, òun ni a ó padà fi wọ̀n fún yín Ó sì pa òwe kan fún wọn Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí ó ba pé, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀ Èéṣe tí ìwọ sì ń wo èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsí ìtì igi tí ń bẹ lójú ara rẹ Tàbí ìwọ ó ti ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, Arákùnrin, jẹ́ kí èmi yọ èérún igi tí ń bẹ lójú rẹ, nígbà tí ìwọ tìkararẹ kò kíyèsí ìtì igi tí ń bẹ lójú rẹ Ìwọ àgàbàgebè, kọ́kọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò lójú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ ó sì tó ríran gbangba láti yọ èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ kúrò Nítorí igi rere kì í so èso búburú bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kì í so èso rere Olúkúlùkù igi ni a ń fi èso rẹ̀ mọ̀ ọn nítorí lórí ẹ̀gún òṣùṣú, ènìyàn kì í ká èṣo ọ̀pọ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ ni lórí ẹ̀gún ọ̀gàn a kì í ká èṣo àjàrà Ènìyàn rere láti inú ìsúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá àti ènìyàn búburú láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun búburú jáde wá nítorí ohun tí ó wà nínú ọkàn ni ẹnu rẹ̀ ń sọ Nítorí náà, èéṣe tí ẹ̀yin ń pè mí ní, Olúwa, Olúwa, tí ẹ̀yin kò sì ṣe ohun tí mo wí Ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ mí wá, tí ó sì ń gbọ́ mi, tí ó sì ń ṣe é, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín Ó jọ Ọkùnrin kan, tí ó kọ́ ilé, tí ó sì wa ilẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta, nígbà tí kíkún omi sì dé, ìgbì omi bì lu ilé náà, kò sì lè mì ín nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́, tí kò sì se é, ó dàbí ọkùnrin tí ó kọ́ ilé sí orí ilẹ̀ láìní ìpìlẹ̀ nígbà tí ìgbì omi bì lù ú, lọ́gán, ó sì wó wíwó ilé náà sì pọ̀ púpọ̀ Ìgbàgbọ́ Ọ̀gágun Róòmù Kan Nígbà tí ó sì pari gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ létí àwọn ènìyàn, ó wọ Kápánáúmù lọ Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ Nígbà tí ó sì gbúròó Jésù, ó rán àwọn àgbààgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀ èdè wa, ó sì ti kọ́ sínágọ́gù kan fún wa Jésù sì ń bá wọn lọ Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ mi láradá Nítorí èmi náà pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí abẹ́ àṣẹ, tí ó ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi, mo sì wí fún ọ̀kan pé, Lọ, a sì lọ àti fún òmíràn pé, Wá, a sì wá àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, Ṣe èyí, a sì ṣe é Nígbà tí Jésù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà á sí i, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ-ọ̀dọ̀ náà tí ń sàìsàn, ara rẹ̀ ti dá Ní ijọ́ kejì, ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Náínì àwọn púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń bá a lọ àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsí i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀ Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, Má sọkún mọ́ Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ àga pósí náà àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́ Ó sì wí pé, Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde! Ẹni tí ó kú náà sì dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fọhùn Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́ Ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé, Wòlíì ńlá dìde nínú wa, àti pé, Ọlọ́run sì wá bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò! Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo Jùdéà, àti gbogbo agbégbé tí ó yí i ká Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù sì sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún un Nígbà tí Jòhánù sì pe àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rán wọn sọ́dọ̀ Jésù, wí pé, Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, Jòhánù Onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn   Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti àrùn, àti ẹ̀mí búburú ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yín rí, tí ẹ̀yín sì gbọ́ fún Jòhánù àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúkún-ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòsì ni à ń wàásù ìyìn rere Alábùkún fún sì ni ẹnikẹ́ni tí kò kọsẹ̀ lára mi Nígbà tí àwọn oníṣẹ Jòhánù padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ síí sọ fún ìjọ ènìyàn ní ti Jòhánù pé, Kí ni ẹ̀yin jáde lọ sí ijù lọ wò Iféfèé tí afẹ́fẹ́ ń mì Ṣùgbọ́n kínni ẹ̀yin jáde lọ wò Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba! Ṣùgbọ́n kíni ẹ̀yin jáde lọ wò Wòlíì Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ! Èyí yìí ni ẹni tí a ti kọ̀wé nítorí rẹ̀ pé  Wò ó, mo rán oníṣẹ́ mi ṣíwájú rẹ ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ Mo wí fún yín nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí wòlíì tí ó pọju Jòhánù Onítẹ̀bọmi lọ ṣùgbọ́n ẹni tí ó kéré jùlọ ní ìjọba Ọlọ́run, ó pọ̀ jù ú lọ Olúwa sì wí pé, Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé Kí ni wọ́n sì jọ Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé  Àwa fọn fèrè fún yín, ẹ̀yin kò jó àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín, ẹ̀yin kò sọkún! Nítorí Jòhánù Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí-wáìnì ẹ̀yin sì wí pé, Ó ní ẹ̀mí èṣù Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu ẹ̀yin sì wí pé, Wò ó, Ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀!  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ gbogbo dá a nipa ọgbọ́n tí ó lò Farisí kan sì rọ̀ ọ́ kí ó wá bá òun jẹun, ó sì wọ ilé Farisí náà lọ ó sì jókòó láti jẹun Sì kíyèsí i, obìnrin kan wà ní ìlú náà, ẹni tí i ṣe ẹlẹ́sẹ̀, nígbà tí ó mọ̀ pé Jésù jókòó, ó ń jẹun ní ilé Farisí, ó mú ṣágo kekeré alabásítà òróró ìkunra wá, Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n Nígbà tí Farisí tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni Jésù sì dáhùn, ó wí fún un pé, Símónì, Mo ní ohun kan sọ fún ọ Ó sì dáhùn pé, Olùkọ́ máa wí Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbésè méjì ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríji àwọn méjèèjì Wí nínú àwọn méjèèjì, tani yóò fẹ́ ẹ jù Símónì dáhùn wí pé, Mo ṣebí ẹni tí ó dáríjìn jù ni Ó wí fún un pé, O wí i re Ó sì yípadà sí obìnrin náà, ó wí fún Símónì pé, Wo obìnrin yìí Èmi wọ ilé rẹ, ìwọ kò fi omi wẹ ẹṣẹ̀ fún mi ṣùgbọ́n òun, omije rẹ̀ ni ó fi ń rọ̀jò sí mi lẹ́sẹ̀ irun orí ni ó fi n nù wọ́n nù Ìwọ kò fi ìfẹnukonu fún mi ṣùgbọ́n òun, nígbà tí mo ti wọ ilé, kò dẹ́kun ẹnu fífi kò mí lẹ́ṣẹ̀ Ìwọ kò fi òróró pa mí lórí, ṣùgbọ́n òun ti fi òróró pa mí lẹ́ṣẹ̀ Ǹjẹ́ mo wí fún ọ, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í nítorí tí ó ní ìfẹ́ púpọ̀ ẹni tí a sì dárí díẹ̀ jì, òun náà ni ó ní ìfẹ́ díẹ̀ Ó sì wí fún un pé, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́! Àwọn tí ó bá a jókòó jẹun sì bẹ̀rẹ̀ síí rò nínú ara wọn pé, Ta ni èyí tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni pẹ̀lú Ó sì dáhùn wí fún obìnrin náà pé, Ìgbàgbọ́ rẹ gbà ọ́ là má a lọ ní àlààáfíà Òwe Afúnrúgbìn Kan Ó sì ṣe lẹ́yìn náà, tí ó ń lá gbogbo ìlú àti ìletò kọjá lọ, ó ń wàásù, ó ń ròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run àwọn méjìlá sì ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, Àti àwọn obìnrin kan, tí a ti mú láradá kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú àti nínú àìlera wọn, Màríà tí a ń pè ní Magidalénè, lára ẹni tí ẹ̀mí èṣù méje ti jáde kúrò Àti Jòánà aya Kúsà tí í ṣe ìríjú Hẹ́rọ́dù, àti Ṣùsánà, àti àwọn púpọ̀ mìíràn, tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún un nínú ohun ìní wọn Nígbà tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn pé jọ pọ̀, àwọn ènìyàn láti ìlú gbogbo sì tọ̀ ọ́ wá, ó fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé Afúrúgbìn kan jáde lọ láti fún irúgbìn rẹ̀ bí ó sì ti ń fúrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ṣà á jẹ Òmíràn sì bọ́ sórí àpáta bí ó sì ti hù jáde, ó gbẹ nítorí tí kò ní ìrinlẹ̀ omi Òmíràn sì bọ́ sínú ẹ̀gún ẹ̀gún sì dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ sókè, ó sì fún un pa Òmíràn sì bọ́ sí ilẹ̀ rere, ó sì hù sókè, ó sì so èso ọrọrún Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí tán, ó náhùn sókè pé, Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, Kí ni a lè mọ òwe yìí sí Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run ṣùgbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn wọn yóò jẹ́ òwe, pé ní rírí,  kí wọn má baà rí, àti ní gbígbọ́ kí ó má lè yé wọn Ǹjẹ́ òwe náà ni èyí irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Àwọn ti ẹ̀bá ọ̀nà ni àwọn tí ó gbọ́ nígbà náà ni Èṣù wá ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn wọn, kí wọn má ba à gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sáà díẹ̀ nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn Àwọn tí ó bọ́ sínú ẹ̀gún ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ tán, wọ́n lọ, wọn a sì fi ìtọ́jú àti ọrọ̀ àti ìrora ayé fún un pa, wọn kò sì lè so èso àsogbó Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso Kò sí ẹnikẹ́ni, nígbà tí ó bá tán fìtílà tan, tí yóò fi ohun èlò bò ó mọ́lẹ̀, tàbí tí yóò gbé e sábẹ́ àketè bí kò ṣe kí ó gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọ ilé lè rí ìmọ́lẹ̀ Nítorí kò sí ohun tí ó farasin, tí a kì yóò fihàn, tàbí ohun tí a fi pamọ́, ti a kì yóò sì mọ̀ kí ó sì yọ sí gbangba Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin má a kíyèsára bí ẹ̀yin ti ń gbọ́ nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní, lọ́wọ́ rẹ̀ ni a ó sì gba èyí tí ó ṣebí òun ní Nígbà náà ní ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn kò sì lè súnmọ́ ọn nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn Wọ́n sì wí fún un pé, Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ dúró lóde, wọn fẹ́ rí ọ Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn wọ̀nyí tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é Ní ijọ́ kan, ó sì wọ ọkọ̀ ojú-omi kan lọ òun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ó sì wí fún wọn pé, Ẹ jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìhà kejì adágún Wọ́n sì ṣíkọ̀ lọ Bí wọ́n sì ti ń lọ, ó sùn ìjì ńlá sì dé, ó ń fẹ́ lójú adágún wọ́n sì kún fún omi, wọ́n sì wà nínú ewu Wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá wọ́n sì jí i, wí pé, Olùkọ́, Olùkọ́, àwa yóò sègbé! Nígbà náà ni ó dìde, ó sì bá ìjì líle àti ríru omi wí wọ́n sì dúró, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì dé Ó sì wí fún wọn pé, Ìgbàgbọ́ yín dà Bí ẹ̀rù ti ń ba gbogbo wọn, tí hà sì ń ṣe wọ́n, wọ́n ń bi ara wọn pé, Irú ọkùnrin wo ni èyí, nítorí ó bá ìjì líle àti ríru omi wí, wọ́n sì gbọ́ tirẹ Wọ́n sì gúnlẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Gádárà, tí ó kọjú sí Gálílì Nígbà tí ó sì sọ̀kalẹ̀, ọkùnrin kan pàdé rẹ̀ lẹ́yìn ìlú náà, tí ó ti ní àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù fún ìgbà pípẹ́, tí kì í wọ aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í jókòó ní ilé kan, bí kò ṣe ní ibojì Nígbà tí ó rí Jésù, ó ké, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí lóhùn rara, pé, Kí ni mo ní í ṣe pẹ̀lú rẹ, Jésù, ìwọ ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá ògo Èmi bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró Jésù sì bí i pé, Orúkọ rẹ Ó sì dáhùn pé, Léjíónì, nítorí ẹ̀mí ẹ̀ṣù púpọ̀ ni ó ti wọ̀ ọ́ lára lọ Wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe rán wọn lọ sínú ọ̀gbun Agbo ẹlẹ́dẹ̀ púpọ̀ sì ń bẹ níbẹ̀ tí ń jẹ lórí òkè wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí àwọn wọ inú wọn lọ Ó sì yọ̀ǹda fún wọn Nígbà tí àwọn ẹ̀mí ẹ̀sù sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ lọ agbo ẹlẹ́dẹ̀ sì tú pẹ̀ẹ́, wọ́n sí súré rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ sì bèbè odò bọ́ sínú adágún náà, wọ́n sì rì sínú rẹ̀ Nígbà tí àwọn tí n bọ́ wọn rí ohun tí ó sẹlẹ̀, wọ́n sá, wọ́n sì lọ, wọ́n sì ròyìn ní ìlú àti ní ilẹ̀ náà Nígbà náà ni wọ́n jáde lọ wo ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sì tọ Jésù wá, wọ́n sì rí ọkùnrin náà, lára ẹni tí àwọn ẹ̀mí èṣù ti jáde lọ, ó jókòó lẹ́bá ẹsẹ̀ Jésù, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì bọ́ sí ipò ẹ̀rù sì bà wọ́n Àwọn tí ó rí i ròyìn fún wọn bí ó ti ṣe mú ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù náà láradá Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn láti ilẹ̀ Gádárà yíká bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi Ó sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojúomi, ó padà sẹ́yìn Ǹjẹ́ ọkùnrin náà tí ẹ̀mí ẹ̀sù jáde kúrò lára rẹ̀, bẹ̀ ẹ́ kí òun lè máa bá a gbé ṣùgbọ́n Jésù rán an lọ, wí pé, Padà lọ sí ilé rẹ, kí o sì sọ ohun tí Ọlọ́run ṣe fún ọ bí ó ti pọ̀ tó Ó sì lọ, o sì ń ròyìn já gbogbo ìlú náà bí Jésù ti ṣe ohun ńlá fún òun tó Ó sì ṣe, nígbà tí Jésù padà lọ, àwọn ènìyàn tẹ́wọ́gbà á nítorí tí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀ Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jáírù, ọ̀kan nínú àwọn olórí sínágọ́gù wá ó sì wólẹ̀ lẹ́bá ẹṣẹ̀ Jésù, ó bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó wá sí ilé òun Nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ó ń kú lọ Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ń há a ní àyè Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, , tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un lára dá, Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ Jésù sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mí Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́ Pétérù àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé, Olùkọ́, àwọn ènìyàn há ọ ní ààyè, wọ́n sì ń bì lù ọ́, ìwọ sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mi Jésù sì wí pé, Ẹnìkan fi ọwọ́ kàn mí nítorí tí èmí mọ̀ pé, àṣẹ jáde lára mi Nígbà tí Obìnrin náà sì mọ̀ pé òun kò farasin, ó wárìrì, ó wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ fún un lójú àwọn ènìyàn gbogbo nítorí ohun tí ó ṣe, tí òun fi fi ọwọ́ kàn án, àti bí a ti mú òun láradá lójúkan náà Ó sì wí fún un pé, Ọmọbìnrin, tújúká ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá máa lọ ní àlààáfíà! Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lẹ́nu, ẹnìkan ti ilé olórí sínágọ́gù wá, ó wí fún un pé, Ọmọbìnrin rẹ kú má yọ olùkọ́ni lẹ́nu mọ́ Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù gbọ́, ó dá a lóhùn, pé, Má bẹ̀rù sá gbàgbọ́ nìkan, a ó sì mú un láradá Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù sì wọ ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé, bí kò ṣe Pétérù, àti Jákọ́bù, àti Jòhánù, àti baba àti ìyá ọmọbìnrin náà Gbogbo wọn sì sọkún, wọ́n pohùnréré ẹkún rẹ̀ ó sì wí fún wọn pé, Ẹ má sọkún mọ́ kò kú, sísùn ni ó sùn Wọ́n sì fi í ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sá mọ̀ pé ó kú Nígbà tí ó sì sé gbogbo wọn mọ́ òde, ó mú un lọ́wọ́, ó sì wí pé, Ọmọbìnrin, dìde! Ẹ̀mí rẹ̀ sì padà bọ̀, ó sì dìde lọ́gán ó ní kí wọn fún un ní oúnjẹ Ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀ ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọn má ṣe wí fún ẹnìkan ohun tí a ṣe Jésù Rán Ọmọ-Ẹ̀yìn Méjìlá Lọ Wàásù Ó sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí ẹ̀sù gbogbo, àti láti wo àrùn sàn Ó sì rán wọn lọ wàásù ìjọba Ọlọ́run, àti láti mú àwọn ọlọkùnrùn láradá Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ má ṣe mú nǹkan lọ fún àjò yín, ọ̀pá, tàbí àpò tàbí àkàrà, tàbí owó bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má sì ṣe ní ẹ̀wù méjì Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin gbé, láti ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin sì ti jáde Iye àwọn tí kò bá si gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò ní ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín fún ẹ̀rí sí wọn Wọ́n sì lọ, wọ́n ń la ìletò kọjá wọ́n sì ń wàásù ìyìn rere, wọ́n sì ń mú ènìyàn láradá níbi gbogbo Hẹ́rọ́dù tẹ́tírákì sì gbọ́ nǹkan gbogbo èyí tí a ṣe láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ó sì dààmú, nítorí tí àwọn ẹlòmíràn ń wí pé, Jòhánù ni ó jíǹde kúrò nínú òkú Àwọn ẹlòmíràn sì wí pé Èlíjà ni ó farahàn àwọn ẹlòmíràn sì wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde Hẹ́rọ́dù sì wí pé, Jòhánù ni mo ti bẹ́ lórí ṣùgbọ́n tani èyí tí èmi ń gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí sí Ó sì ń fẹ́ láti rí i Nígbà tí àwọn àpósítélì sì padà dé, wọ́n ròyìn ohun gbogbo fún un tí wọ́n ti ṣe Ó sì mú wọn, ó sì lọ sí apákan níbi ijù sí ìlú tí a ń pè ní Bẹtiṣáídà Nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì mọ̀, wọ́n tẹ̀lé e ó sì gbà wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún wọn àwọn tí ó fẹ́ ìmúláradá, ni ó sì mú láradá Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rẹlẹ̀, àwọn méjìlá wá, wọ́n sì wí fún un pé, Tú ìjọ ènìyàn ká, kí wọn lè lọ sí ìletò àti sí ìlú yíká, kí wọn lè wò, àti kí wọn lè wá oúnjẹ níbi ijù ni àwa sá wà níhín-ín Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, Ẹ fi oúnjẹ fún wọn jẹ! Wọ́n sì wí fún un pé, Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-un lọ, pẹ̀lú ẹja méjì bí kò ṣe pé àwa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí Nítorí àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn, ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Kí wọ́n mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ní àràádọ́ta Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì mú gbogbo wọn jókòó Nígbà náà ni ó mú ìṣù àkàrà márùn-un, àti ẹja méjì náà, nígbà tí ó gbé ojú sókè, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fifún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí wọn gbé e kalẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn Wọ́n sì jẹ, gbogbo wọn sì yó wọ́n ṣa apẹ̀rẹ̀ méjìlá jọ nínú àjẹkù tí ó kù fún wọn Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì bi wọ́n pé, Ta ni àwọn ènìyàn ń fi èmi pè Wọ́n sì dáhùn wí pé, Jòhánù Onítẹ̀bọmi ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ní Èlíjà ni àti àwọn ẹlòmíràn wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde Ó sì bi wọ́n pé, Ṣùgbọ́n tani ẹ̀yin ń fi èmi pè Pétérù sì dáhùn, wí pe, Kírísítì ti Ọlọ́run Ó sì kìlọ̀ fún wọn, ó sì pàṣẹ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan Ó sì wí pé, Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ijọ́ kẹta a ó sì jí i dìde Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti má a tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là Nítorí pé èrè kínni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó ṣòfò Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni ọmọ ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn ańgẹ́lì mímọ́ Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìnín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ijọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Pétérù àti Jòhánù àti Jákọ́bù, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbò, Sì kíyèsí i, àwọn ọkùnrin méjì, Mósè àti Èlíjà, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀ Tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerúsálémù Ṣùgbọ́n ojú Pétérù àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Pétérù wí fún Jésù pé, Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mósè, àti ọ̀kan fún Èlíjà Bí ó ti ń sọ báyìí, ìkùukù kan wá, ó ṣíji bò wọ́n ẹ̀rù sì bà wọ́n nígbà tí wọ́n ń wọ inú ìkùukù lọ Ohùn kan sì ti inú ìkùukùu wá wí pé, Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi ẹ máa gbọ́ tirẹ̀ Nígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jésù nìkan ṣoṣo ni a rí Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí Ó sì ṣe, ní ijọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wá pàdé rẹ̀ Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan nínú ìjọ kígbe sókè, pé Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni Sì kíyèsí i, ẹ̀mí ẹ̀sù a máa mú un, a sì máa kígbe lójijì a sì máa nà án tàntàn títí yóò fi yọ ìfófòó lẹ́nu, a máa pa á lára, kì í tilẹ̀ ń fẹ́ fi í sílẹ̀ lọ Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde wọn kò sì lè ṣe é Jésù sì dáhùn pé, Ìran aláìgbàgbọ́ àti àrékérekè, èmi ó ti bá yín gbé pẹ́ tó Èmi yóò sì ti ṣe sùúrù fún yín pẹ́ tó Fa ọmọ rẹ wá níhín-ín yìí Bí ó sì ti ń bọ̀, ẹ̀mí ẹ̀sù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì nà án tàntàn Jésù sì bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sì mú ọmọ náà láradá, ó sì fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́ Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí iṣẹ́ ọláńlá Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nígbà tí hà sì ń ṣe gbogbo wọn sí ohun gbogbo tí Jésù ṣe, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wọ̀ yín léti nítorí a ó fi ọmọ-ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ó sì ṣú wọn lójú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ̀ ọ́n ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bèèrè ìdí ọ̀rọ̀ náà Iyàn kan sì dìde láàrin wọn, ní ti ẹni tí yóò ṣe olórí nínú wọn Nígbà tí Jésù sì mọ ìrò ọkàn wọn, ó mú ọmọdé kan, ó gbé e jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ Ó sì wí fún wọn pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọdé yìí nítorí orúkọ mi, ó gbà mí àti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi nítorí ẹni tí ó bá kéré jù nínú gbogbo yín, òun náà ni yóò pọ̀ Jòhánù sì dáhùn ó sì wí fún un pé, Olùkọ́, àwá rí ẹnìkan ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èsù jáde àwa sì dá a lẹ́kun, nítorí tí kò bá wa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Jésù sì wí fún un, pé, Má ṣe dá a lẹ́kun mọ́ nítorí ẹni tí kò bá lòdì síi yín, ó wà fún yín Nígbà tí ọjọ́ àti gbà á sókè ń súnmọ́, ó fi ojú lé ọ̀nà láti lọ sí Jerúsálémù Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀ nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaríà láti pèṣè sílẹ̀ dè é Wọn kò sì gbà á, nítorí ojú rẹ̀ dàbí ẹni pé ó ń lọ sí Jerúsálémù Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Jákọ́bù àti Jòhánù sì rí i, wọ́n ní, Olúwa wa, jẹ́ kí a pe iná láti ọ̀run wá, kí a sì pa wọ́n run, Ṣùgbọ́n Jésù yípadà, ó sì bá wọn wí, Nítorí ọmọ ènìyàn kò wá láti pa ẹ̀mí ènìyàn run, bí kò ṣe láti gbà á là Wọ́n sì lọ sí ìletò mìíràn Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ọkùnrin kan wí fún un pé, Olúwa, Èmi ń fẹ́ láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ Jésù sì wí fún un pé, Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́ ṣùgbọ́n ọmọ ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé Ó sì wí fún ẹlòmíràn pé, Máa tọ̀ mí lẹ́yìn Ṣùgbọ́n èyí wí fún un pé, Olúwa, jẹ́ kí èmi lọ sìnkú baba mi ná Jésù sì wí fún un pé, Jẹ́ kí àwọn òkú máa sìnkú ara wọn ṣùgbọ́n ìwọ lọ kí o sì máa wàásù ìjọba Ọlọ́run Ẹlòmíràn sì wí fún un pé, Olúwa, èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbéré fún àwọn ará ilé mi Jésù sì wí fún un pé, Kò sí ẹni, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun èlò ìtùlẹ̀, tí ó sì wo ẹ̀yìn, tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọ́run Ọlọ́run Fẹ́ràn Jákọ́bù, Ó Sì Kórìíra Ísọ̀ Ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa sí Ísírẹ́lì láti ẹnu Málákì Èmí ti fẹ́ ẹ yín, ni Olúwa wí Ṣùgbọ́n ẹ̀yín béèrè pé, Báwo ni ìwọ ṣe fẹ́ wa Ísọ̀ kì í ha ṣe arákùnrin Jákọ́bù bí ni Olúwa wí Ṣíbẹ̀ èmi fẹ́ràn Jákọ́bù, ṣùgbọ́n Ísọ̀ ni èmi kórìíra, mo ti sọ àwọn òkè-ńlá rẹ̀ di aṣálẹ̀, mo sì fi ìní rẹ̀ fún àwọn akáta ihà Édómù lè wí pé, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a run wá, àwa yóò padà wá, a ó sì tún ibùgbé náà kọ́ Ṣùgbọ́n èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun wí pé Àwọ́n lè kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò wó palẹ̀ Wọn yóò sì pè wọ́n ní Ilẹ̀ Búburú, àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń wà ní ìbínú Olúwa Ẹ̀yin yóò sì fi ojú yín rí i, ẹ̀yin yóò sì wí pé, Títóbi ni Olúwa , títóbi rẹ̀ tayọ kọjá agbègbè Ísírẹ́lì Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ-ọ̀dọ̀ a sì máa bọlá fún ọ̀gá rẹ̀ Bí èmí bá jẹ́ baba ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ sí mi dà Bí èmi bá sì jẹ́ ọ̀gá ọlá, tí ó tọ́ sí mi dà ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ ọ̀ mi Ṣùgbọ́n ẹ̀yín béèrè pé, Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ ọ̀ rẹ Ẹ̀yín gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ ẹ̀ mi Ẹ̀yín sì tún béèrè pé, Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ Nípa sísọ pé tábìlì Olúwa di ẹ̀gàn Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé ìyẹn kò ha burú bí Nígbà tí ẹ̀yin fi amúkùnún àti aláìsàn ẹran rúbọ, ṣé ìyẹn kò ha bògìrì bí Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rúbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín Ṣé yóò gbà yín ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrin yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹ́ḿpìlì, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ ọ yín Orúkọ mi yóò tóbi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀ oòrùn Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ ọ̀ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Nítorí ẹ̀yin ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, Tábìlì Olúwa di àìmọ́ àti èso rẹ̀, àní oúnjẹ́ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí! Ẹ̀yin sì yínmú sí i, ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó farapa, arọ àti olókùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rúbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín ni Olúwa wí Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà, tí ó ni akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀, tí ó sì ṣe ìlérí láti fi lélẹ̀ tí ó sì fi ẹ̀ran tó lábùkù rúbọ sí Olúwa nítorí Ọba ńlá ni Èmi, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè Ìkìlọ̀ Fún Àwọn Àlùfáà Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ẹ̀yin àlùfáà, òfin yìí ní fún yín Bí ẹ̀yin kò bá ni gbọ́, bí ẹ̀yin kò bá ní fi í sí àyà láti fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí èmi yóò sì ran ègún sí orí yín, èmi yóò sì fi ìbùkún yín ré Nítòótọ́ mó ti fi ré ná, nítorí pé, ẹ̀yin kò fi sí ọkàn yín láti bu ọlá fún mi Nítorí ti yín èmí yóò ba àwọn ọmọ yín wí èmi ó sì fi ìgbẹ́ rẹ́ yín lójú, àní àwọn ìgbẹ́ ọrẹ ọwọ́ yín wọ̀nyí, a ó sì kó yín lọ pẹ̀lú rẹ̀ Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé, èmi ni ó ti rán òfin yìí sí yín, kí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Léfì lè tẹ́ṣíwájú ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Májẹ̀mu mi wà pẹ̀lú rẹ̀, májẹ̀mu ti ìyè àti àlàáfíà wà pẹ̀lú rẹ̀ mo sì fi wọn fún un, nítorí bíbẹ̀rù tí ó bẹ̀rù mi, tí ẹ̀rù orúkọ mi sì bà á Òfin òtítọ́ wà ni ẹnu rẹ̀, a kò sì rí irọ́ ni ètè rẹ̀ ó ba mi rìn ní àlàáfíà àti ni ídúró ṣinṣin, ó sì yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Nítorí ètè àlùfáà ní a ti máa pa ìmọ̀ mọ́, kí àwọn ènìyàn lè máa wá ìtọ́ni ni ẹnu rẹ̀ nítorí òun ni iransẹ Olúwa àwọn ọmọ ogun Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yapa kúrò ní ọ̀nà náà ẹ̀yin sì ti fi ìkọ́ni yín mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀ ẹ̀yin ti ba májẹ̀mú tí mo da pẹ̀lú Léfì jẹ́, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Nítorí náà ni èmi pẹ̀lú ṣe sọ yín di ẹ̀gàn, àti ẹni àìkàsí níwájú gbogbo ènìyàn, nítorí ẹ̀yin kò tẹ̀lé ọ̀nà mi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń ṣe ojúṣàájú nínú òfin Baba kan náà kí gbogbo wa ha ní Ọlọ́run kan náà kọ́ ni ó dá wa bí Nítorí kín ni àwa ha ṣe sọ májẹ̀mú àwọn baba wa di aláìmọ nípa híhùwà àrékérekè olúkulùkù sí arákùnrin rẹ̀ Júdà ti ń hùwà àrékérekè, a sì ti hùwà ìríra ní Ísírẹ́lì àti ni Jérúsálẹ́mù nítorí Júdà tí ṣe eyi ti ó lè sọ ibi mímọ́ Olúwa di aláìmọ́ nípa gbígbé ọmọbìnrin ọlọ́run àjèjì ni ìyàwó Ní ti ẹni tí ó se èyí, ẹni tí ó wù kí ó jẹ, kí Olúwa kí ó gé e kúrò nínú àgọ́ Jákọ́bù, bí ó tilẹ̀ mú ẹbọ ọrẹ wá fún Olúwa àwọn ọmọ ogun Èyí ni ohun mìíràn tí ẹ̀yin sì tún ṣe Ẹ̀yin fi omijé bo pẹpẹ Olúwa mọ́lẹ̀ Ẹ̀yín sọkún, ẹ̀yín sì ba ara jẹ́ nítorí tì Òun kò ka ọrẹ yín sí mọ́, tàbí kí ó fi inú dídùn gba nǹkan yìí lọ́wọ́ yín Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, Nítorí kín ní Nítorí Olúwa ti ṣe ẹlẹ́rìí láàrin ìwọ àti láàrin aya èwe rẹ, ẹni tí ìwọ ti ń hùwà ẹ̀tàn síi bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkeji rẹ ni òun jẹ́, àti aya májẹ̀mú rẹ Ọlọ́run kò hà ti ṣe wọ́n ní ọ̀kan Ni ara àti ni ẹ̀mí tirẹ̀ ni Èéṣe tí Ọlọ́run da yín l'ọ́kàn Kí òun bá à lè wá irú ọmọ bí ti Ọlọ́run Nítorí náà, ẹ tọ́jú ẹ̀mí yín, ẹ má sì ṣe hùwà ẹ̀tàn sí aya èwe yín Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀, ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, bẹ́ẹ̀ ni mo kóríra kí èníyàn máa fi ipá bó ara rẹ̀ àti pẹ̀lú asọ rẹ̀, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Nítorí náà ẹ sọ́ ẹ̀mí yín, kí ẹ má se hùwà ẹ̀tàn Ẹ̀yin ti fi ọ̀rọ̀ yin dá Olúwa ní agara Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèré pé, Nínú kín ni àwa fi dá a lágara Nígbà tí ẹ̀yìn wí pé, Gbogbo ẹni tí ó ṣe ibi, rere ni níwájú Olúwa , inú rẹ̀ sì dùn sí wọn, tabi Níbo ni Ọlọ́run ìdájọ́ gbé wà Rírán Mèsáyà náà Wò ó, Èmi yóò ran ìránṣẹ mi, yóò si tún ọ̀nà ṣe ṣáájú mi Nígbà náà ni Olúwa , tí ẹ̀yin ń wa, yóò dé ni òjijì sí tẹ́ḿpìlì rẹ̀ àní oníṣẹ́ májẹ̀mú náà, tí inú yín dùn sí, yóò dé, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Ṣùgbọ́n ta ni o lè fi ara da ọjọ́ dídé rẹ̀ Ta ni yóò sì dúró nígbà tí ó bá fi ara hàn Nítorí òun yóò dàbí iná ẹni tí ń da fàdákà àti bi ọṣẹ alágbàfọ̀ Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà yóò wẹ àwọn ọmọ Léfì mọ́, yóò sì tún wọn dà bí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún Olúwa , nígbà náà ni ọrẹ Júdà àti ti Jérúsálẹ́mù yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa , gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ àtijọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ọdún ìgbàanì Èmi ó sì súnmọ́ yin fún ìdájọ́ Èmi yóò sì yára ṣe ẹlẹ́rìí sí àwọn oṣó, sí àwọn panṣágà, sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó fi ọ̀yà alágbàṣe dù ú, àti àwọn tí ó ni àwọn opó àti àwọn aláìní baba lara, àti sí ẹni tí kò jẹ́ kí àlejò rí ìdájọ́ òdodo gbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Èmi Olúwa kò yípadà Nítorí náà ni a kò ṣe run ẹ̀yin ọmọ Jákọ́bù Láti ọjọ́ àwọn baba-ńlá yín wá ni ẹ̀yin tilẹ̀ ti kọ ẹ̀yìn sí ìlànà mi, tí ẹ kò sì pa wọ́n mọ́ Ẹ padà wá sí ọ̀dọ̀ mi, Èmi yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, Báwo ni àwa yóò se padà Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, Báwo ni àwa ṣe jà ọ́ ní olè Nípa ìdámẹ́wàá àti ọrẹ Ríré ni a ó fi yín ré gbogbo orílẹ̀ èdè yìí, nítorí ẹ̀yin ti jà mi lólè Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ báà lè wà ní ilé mi, ẹ fi èyí dán mi wò, ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, kí ẹ sì wò bí èmi kò bá ní sí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yin, kí èmi sì tú ìbùkún àkúnwọ́ sílẹ̀ jáde fún yín, tóbẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì àyè láti gbà á Èmi yóò sì bá kòkòrò ajẹnirun wí nítorí yín, òun kò sì ni run èso ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni àjàrà inú oko yín kò ní rẹ̀ dànù, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Nígbà náà ni gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sì pè yín ni alábùkún fún, nítorí ti yín yóò jẹ́ ilẹ̀ tí ó wuni, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Ẹ̀yin ti sọ ọ̀rọ̀ líle sí mi, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin béèrè pé, Ọ̀rọ̀ kín ni àwa sọ sí ọ Ẹ̀yín ti wí pé, Asán ni láti sin Ọlọ́run Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń sọ̀fọ̀ ní iwájú Olúwa àwọn ọmọ ogun Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí àwa pé agbéraga ni alábùkún fún Ní otitọ ni àwọn ti ń ṣe búburú ń gbèrú sí i, kódà àwọn ti ó dán Olúwa wò ni a dá sí   Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa ń ba ara wọn sọ̀rọ̀, Olúwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́ A sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí o bẹ̀rù Olúwa , ti wọn sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀ Wọn yóò sì jẹ́ tèmi, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, ni ọjọ́ náà, tí èmi ó dá èmi yóò sì da wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí máa ń dá ọmọ rẹ̀ tí yóò ń sìn ín sí Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìyàtọ̀, ìyàtọ̀ láàrin olódodo àti ẹni búburú, láàrin ẹni tí ń sìn Ọlọ́run, àti ẹni tí kò sìn ín Ọjọ́ Dájúdájú, ọjọ́ náà ń bọ̀ tí yóò máa jó bi iná ìléru Gbogbo àwọn agbéraga, àti gbogbo àwọn olùṣe búburú yóò dàbí àgékù koríko ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò si jó wọn run, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, Ti ki yóò fi kù gbòǹgbò kan tàbí ẹ̀ka kan fún wọn Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, òòrùn ododo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúlárada ni ìyẹ́ apá rẹ̀ Ẹ̀yin yóò sì jáde lọ, ẹ̀yin yóò sì máa fò fún ayọ̀ bi àwọn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù tí a tú sílẹ̀ lórí ìso Ẹ̀yin yóò sì tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ nítorí wọn yóò di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ náà tí èmi yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Ẹ rántí òfin Mósè ìránṣẹ́ mi, àwọn ìlànà àti òfin èyí tí mo fún un ní Hórébù fún gbogbo Ísírẹ́lì Wò ó, èmi yóò rán wòlíì Èlíjà sí i yín, ki ọjọ́ ńlá, ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa to dé Òun yóò sì pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sì ti àwọn baba wọn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò wá, èmi yóò sì fi ilẹ̀ náà gégùn-ún Àkọsílẹ̀ ìwé ìran Jésù Kírísítì Ìran Jésù Kírísítì, ẹni tí í ṣe ọmọ Dáfídì, ọmọ Ábúráhámù Ábúráhámù ni baba Ísáákì Ísáákì ni baba Jákọ́bù Jákọ́bù ni baba Júdà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, Júdà ni baba Pérésì àti Ṣérà, Támárì sì ni ìyá rẹ̀, Pérésì ni baba Ésírónù Ésírónù ni baba Rámù Rámù ni baba Ámínádábù Ámínádábù ni baba Náhísónì Náhísónì ni baba Sálímónì Sálímónì ni baba Bóásì, Ráhábù sí ni ìyá rẹ̀ Bóásì ni baba Óbédì, Rúùtù sí ni ìyá rẹ̀ Óbédì sì ni baba Jésè Jésè ni baba Dáfídì ọba Dáfídì ni baba Sólómónì, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Húráyà tẹ́lẹ̀ rí Sólómónì ni baba Réhóbóámù, Réhóbóámù ni baba Ábíjà, Ábíjà ni baba Ásà, Áṣà ni baba Jéhósáfátì Jéhósafátì ni baba Jéhórámù Jéhórámù ni baba Húsáyà Húsáyà ni baba Jótámù Jótámù ni baba Áhásì Áhásì ni baba Heṣekáyà Heṣekáyà ni baba Mánásè Mánásè ni baba Ámónì Ámónì ni baba Jósáyà Jósáyà sì ni baba Jékónáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Bábílónì Lẹ́yìn ìkólọ sí Bábílónì Jékónáyà ni baba Selítílì Selítílì ni baba Sérúbábélì Sèrérúbábélì ni baba Ábíúdì Ábíúdì ni baba Élíákímù Élíákímù ni baba Ásórì Ásórì ni baba Sádókù Sádókù ni baba Ákímù Ákímù ni baba Élíúdì Élíúdì ni baba Élíásárì Élíásárì ni baba Mátítánì Mátítánì ni baba Jákọ́bù Jákọ́bù ni baba Jósẹ́fù, ẹni tí ń ṣe ọkọ Màríà, ìyá Jésù, ẹni tí í ṣe Kírísítì Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Ábúráhámù dé orí Dáfídì, ìran mẹ́rìnlà á láti orí Dáfídì títí dé ìkólọ sí Bábílónì, àti ìran mẹ́rìnlà láti ìkólọ títí dé orí Kírísítì Bí a ṣe bí Jésù nì yìí Ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrin Màríà ìyá rẹ̀ àti Jósẹ́fù, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ Nítorí Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòótọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójú tì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, ańgẹ́lì Olúwa yọ sí i ní oju àlá, ó wí pé, Jósẹ́fù, ọmọ Dáfídì, má fòyà láti fi Màríà ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé Wúndíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, a ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Èmánúẹ́lì, èyí tí ó túmọ̀ sí, Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa Nígbà tí Jósẹ́fù jí lójú oorun rẹ̀, òun ṣe gẹ́gẹ́ bí ańgẹ́lì Olúwa ti pàṣẹ fún un Ó mú Màríà wá sílé rẹ̀ ní aya Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ ọ́n títítí ó fi bí ọmọkùnrin, òun sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jésù Jésù Rán Àwọn Méjìlá Jáde Jésù sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀ ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn àrùn àti àìsàn gbogbo Orúkọ àwọn àpósítélì méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí ẹni àkọ́kọ́ ni Símónì ẹni ti a ń pè ni Pétérù àti arákùnrin rẹ̀ Ańdérù, Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti arákùnrin rẹ̀ Jòhánù Fílípì àti Bátólómíù Tómásì àti Mátíù agbowó òde Jákọ́bù ọmọ Álíféù àti Tádéù Símónì ọmọ ẹgbẹ́ Sílíọ́tì, Júdásì Ísíkáríọ́tù, ẹni tí ó da Jésù Jésù ran àwọn méjèèjìla yìí jáde, pẹ̀lú àṣẹ báyìí pé Ẹ má ṣe lọ sì àárín àwọn aláìkọlà tàbí wọ̀ èyíkèyìí ìlú àwọn ará Samáríà Ẹ kúkú tọ̀ àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí ó nù lọ Bí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ máa wàásù yìí wí pé Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀ Ẹ máa ṣe ìwòṣan fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn okú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí-èṣù jáde Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbàá, ọ̀fẹ́ ni kú ẹ fi fún ni Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín Ẹ má ṣe mú àpo fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un Ìlúkílùú tàbí ìletòkíletò tí ẹ̀yin bá wọ̀, ẹ wá ẹni ti ó bá yẹ níbẹ̀ rí, níbẹ̀ ni kí ẹ sì gbé nínú ilé rẹ̀ títítí ẹ̀yin yóò fi kúrò níbẹ̀ Nígbà tí ẹ̀yin bá sì wọ ilé kan, ẹ kí i wọn Bí ilé náa bá sì yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó bà sórí rẹ̀ ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó padà sọ́dọ̀ yín Bí ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tàbí tí kò gba ọ̀rọ̀ yín, ẹ gbọn eruku ẹ̀ṣẹ̀ yín sílẹ̀ tí ẹ bá ń kúrò ní ilé tàbí ìlú náà Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò sàn fún ìlú Sódómù àti Gòmórà ní ọjọ́ ìdájọ́ ju àwọn ìlú náà lọ Mò ń rán yín lọ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàrin ìkookò Nítorí náà, kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nítorí wọn yóò fi yín le àwọn ìgbìmọ̀ ìgbéríko lọ́wọ́ wọn yóò sì nà yín nínú sínágọ́gù Nítorí orúkọ mi, a ó mú yín lọ ṣíwájú àwọn baálẹ̀ àti àwọn ọba, bí ẹlẹ́rìí sí wọn àti àwọn aláìkọlà Nígbà tí wọ́n bá mú yín, ẹ má ṣe ṣàníyàn ohun tí ẹ ó sọ tàbí bí ẹ ó ṣe sọ ọ́ Ní ojú kan náà ni a ó fi ohun tí ẹ̀yin yóò sọ fún yín, Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ó sọ ọ́, bí kò ṣe Ẹ̀mí Baba yín tí ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín Ọmọ-ìyá méjì yóò ṣe ikú pa ara wọ́n Baba yóò fi àwọn ọmọ rẹ̀ fún ikú pa Àwọn ọmọ yóò sọ̀tẹ̀ sí òbí wọn, wọn yóò sì mú kí a pa wọ́n Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà Nígbà tí wọn bá ṣe inúnibíni sì i yín ní ìlú kan, ẹ sá lọ sì ìlú kejì Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kò tì í le la gbogbo ìlú Ísírẹ́lì já tán kí Ọmọ Ènìyàn tó dé Akẹ́kọ̀ọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ-ọ̀dọ̀ kì í ju ọ̀gá rẹ̀ lọ Ó tọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti dà bí olùkọ́ rẹ̀ àti fún ọmọ-ọ̀dọ̀ láti rí bí ọ̀gá rẹ̀ Nígbà tí wọ́n bá pe baálé ilé ní Béélísébúbù, mélòó mélòó ni ti àwọn ènìyàn ilé rẹ̀! Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun to bò tí kò níí fara hàn, tàbí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní mọ̀ ni gbangba Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀ Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan ṣùgbọ́n tí wọn kò lé pa ẹ̀mí Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa Ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run apáàdì Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan Ṣíbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lulẹ̀ lẹ́yìn Baba yin Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú ènìyàn, òun náà ni èmi yóò jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mí ní níwájú àwọn ènìyàn, òun náà ni èmi náà yóò sọ wí pé n kò mọ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run Ẹ má ṣe rò pé mo mú àlàáfíà wá sí ayé, Èmi kò mú àlàáfíà wá bí kò ṣe idà Nítorí èmi wá láti  ọmọkùnrin ní ipa sí bàbá rẹ̀, ọmọbìnrin ní ipa sí ìyá rẹ̀, àti aya ọmọ sí ìyakọ rẹ̀… Ará ilé ènìyàn ni yóò sì máa ṣe ọ̀tá rẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn bàbá rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ kò yẹ ní tèmi, ẹnikẹ́ni tí ó ba fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin jù mí lọ kò yẹ ní tèmi Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀ lé mi kò yẹ ní tèmi Ẹni tí ó bá rí ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i Ẹni tí ó bá gbà yín, ó gbà mí, ẹni tí ó bá sì gbà mí gba ẹni tí ó rán mi Ẹni tí ó ba gba wòlíì, nítorí pé ó jẹ́ wòlíì yóò jẹ èrè wòlíì, ẹni tí ó bá sì gba olódodo nítorí ti ó jẹ́ ènìyàn olódodo, yóò jẹ èrè olódodo Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ago omi tútú fún ọ̀kan nínú àwọn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mu nítorí tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, ọ̀títọ́ ni mo wí fún yín, kò ní pàdánù èrè rẹ̀ Jésù àti Jòhánù onítẹ̀bọmi Lẹ́yìn ìgbà tí Jésù sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó ti ibẹ̀ rékọjá láti máa kọ́ni àti láti máa wàásù ní àwọn ìlú Gálílì gbogbo Nígbà tí Jòhánù gbọ́ ohun tí Kírísítì ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn Jésù dáhùn ó wí pé, Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Jòhánù ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí Àwọn afójú ń ríran, àwọn amúkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́ràn, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìyìn rere fún àwọn òtòsì Alábùkún fún ni ẹni tí kò rí ohun ìkọ̀sẹ̀ nípa mi Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù ti lọ tán, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Jòhánù Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginijù Iféfé tí afẹ́fẹ́ ń mi Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ni ẹ̀yin lọ òde lọ í wò Ọkùnrin tí a wọ̀ ni aṣọ dáradára Rárá àwọn ti ó wọ aṣọ dáradára wà ní ààfin ọba Àní kí ní ẹ jáde láti lọ wò Wòlíì Bẹ́ẹ̀ ni, mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ Èyí ni ẹni tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé  Èmi yóò rán ìránṣẹ́ mi ṣíwájú rẹ, ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ Lóòótọ̀ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Jòhánù onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀ jù ú lọ Láti ìgbà ọjọ́ Jòhánù onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di àfagbárawọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó wí tẹ́lẹ̀ kí Jòhánù kí ó tó dé Bí ẹ̀yin yóò bá gbà á, èyí ni Èlíjà tó ń bọ̀ wá Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ Kí ni èmi ìbá fi ìran yìí wé Ó dàbí àwọn ọmọ kékéré tí ń jókòó ní ọjà tí wọ́n sì ń ké pe àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn  Àwa ń fun fèrè fún yín, ẹ̀yin kò jó àwa kọrin ọ̀fọ̀ ẹ̀yin kò káàánú Nítorí Jòhánù wá kò bá a yín jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ẹ̀yin sì wí pé, Ó ní ẹ̀mí èṣù Ọmọ ènìyàn wá bá a yín jẹun, ó sì bá yin mu, wọ́n wí pé, ọ̀jẹun àti ọ̀mùtì ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀, ṣùgbọ́n a dá ọgbọ́n láre nípa ìṣe rẹ̀ Nígbà náà ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìlú tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ wí, nítorí wọn kò ìronúpìwàdà Ó wí pé, Ègbé ni fún ìwọ Kórásínì, ègbé ni fún ìwọ Bẹtisáídà! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a se nínú yín ní Tírè àti Sídónì, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà tipẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tírè àti Sídónì ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín Àti ìwọ Kápánámù, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run , Rárá a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sódómù, òun ìbá wà títí di òní Lóòótọ́ yóò sàn fún ilẹ̀ Sódómù ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ìwọ lọ Nígbà náà ni Jésù wí pé, Mo yìn ọ Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, nítorí ìwọ ti fi òtítọ́ yìí pamọ́ fún àwọn tó jẹ́ ọlọgbọ́n àti amòyé, Ìwọ sì ti fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí ó wù ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ Ohun gbogbo ni Baba mi ti fi sí ìkáwọ́ mi Kò sí ẹni tí ó mọ ọmọ bí kò se Baba, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ Baba, bí kò ṣe ọmọ, àti àwọn tí ọmọ yan láti fi ara hàn fún Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wí wúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi Ẹ gbé àjàgà mi wọ̀ Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi nítorí onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin yóò sì fi ìsinmi fún ọkàn yín Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́ Olúwa ọjọ́ Ìsinmi Ní àkókò náà ni Jésù ń la àárin oko ọkà kan lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ebi sì ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ya orí ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́ Nígbà tí àwọn Farisí rí èyí Wọ́n wí fún pé, Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi Jésù dáhùn pé, Ẹ̀yin kò ha ka ohun tí Dáfídì se nígbà tí ebi ń pa á àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò se fún àwọn àlùfáà nìkan Tàbí ẹ̀yin kò ti kà á nínú òfin pé ní ọjọ́ ìsinmi, àwọn àlùfáà tí ó wà ní tẹ́ḿpílì ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ tí wọ́n sì wà láì jẹ̀bi Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ẹni tí ó pọ̀ ju tẹ́ńpílì lọ wà níhìn-ín Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí, Àánú ni èmi ń fẹ́ kì í se ẹbọ, ẹ̀yin kì bá tí dá aláìlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi Nítorí pé Ọmọ Ènìyàn jẹ́ Olúwa ọjọ́ ìsinmi Nígbà tí Jésù kúrò níbẹ̀ ó lọ sí sínágọ́gù wọn, ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ wà níbẹ̀ Wọ́n ń wá ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jésù, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ènìyàn láradá ní ọjọ́ ìsinmi Ó dá wọn lóhùn pé, Bí ó bá jẹ́ wí pé bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ní àgùntàn kan ṣoṣo, tí ó sì bọ́ sínú kòtò ní ọjọ́ ìsinmi, tí kì yóò dì í mú, kí ó sì fà á jáde Ǹjẹ́ mélòó mèlòó ní ènìyàn ní iye lórí ju àgùntàn kan lọ! Nítorí náà ó yẹ láti ṣe rere ní ọjọ́ ìsinmi Nígbà náà, ó sì wí fún ọkùnrin náà pé, Na ọwọ́ rẹ, bí òun sì ti nà án, ọwọ́ rẹ̀ sì bọ̀ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ìkejì Síbẹ̀ àwọn Farisí jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un bí wọn yóò ṣe pa Jésù Ṣùgbọ́n Jésù mọ, ó yẹra kúrò níbẹ̀ Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe sọ ẹni ti òun jẹ́ Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àṣọtẹ́lẹ̀ èyí tí wòlíì Àìsáyà sọ nípa rẹ̀ pé Ẹ wo ìránṣẹ mi ẹni tí mo yàn Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ orílẹ̀-èdè gbogbo Òun kì yóò jà bẹ́ẹ̀ ni kì yóò kígbe ẹnikẹ́ni kì yóò gbọ́ ohùn rẹ ní ìgboro Ìyẹ́ tí ó fẹ́rẹ̀ fò ni kí yóò ṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò pa iná fìtílà tí ó rú èéfín Títí yóò fi mú ìdájọ́ dé ìsẹ́gun Ní orúkọ rẹ̀ ni gbogbo ayé yóò fi ìrètí wọn sí Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹmí-èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi Jésù sì mú un lára dá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn Wọ́n wí pé, Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dáfídì bí Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisí gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, Nípa Béélísébúbù nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí-èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí-èṣù jáde Jésù tí ó mọ èrò wọn, ó wí fún wọn pé, Ìjọba kíjọba tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ yóò parun, ìlú kílu tàbí ilé kílé tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ kì yóò dúró Bí èṣù bá sì ń lé èṣù jáde, a jẹ́ wí pé, ó ń yapa sí ara rẹ̀ Ìjọba rẹ yóò ha ṣe le dúró Àti pé, bi èmi bá ń lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù jáde nípa Béélísébúbù, nípa ta ni àwọn ènìyàn yín fi ń lé wọn jáde Nítorí náà ni wọn yóò ṣe má ṣe ìdájọ́ yín Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípa ẹ̀mí Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín Tàbí, báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè wọ ilé alágbára lọ kí ó sì kó ẹrù rẹ̀, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ de alágbára náà Nígbà náà ni ó tó lè kó ẹrù rẹ̀ lọ Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, òun lòdì sí mi, ẹni tí kò bá mi kó pọ̀ ń fọ́nká Nítorí èyí, mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀ òdì ni a yóò dárí rẹ̀ ji ènìyàn, ṣùgbọ́n ìsọ̀rọ̀-òdì-sí ẹ̀mí mímọ́ kò ní ìdáríjì Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ọmọ ènìyàn, a ó dárí jì í, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí jì í, ìbá à ṣe ní ayé yìí tàbí ní ayé tí ń bọ̀ E ṣọ igi di rere, èso rẹ̀ a sì di rere tàbí kí ẹ sọ igi di búburú, èso rẹ a sì di búburú, nítorí nípa èso igi ni a ó fi mọ̀ ọ́n Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ̀yin tí ẹ jẹ búburú ṣe lè sọ̀rọ̀ rere Ọkàn ènìyàn ni ó ń darí irú ọ̀rọ̀ tí ó lè jáde lẹ́nu rẹ̀ Ẹni rere láti inú ìsúra rere ọkàn rẹ̀ ní i mú ohun rere jáde wá àti ẹni búburu láti inú ìsúra búburú ni mu ohun búburú jáde wá Ṣùgbọ́n, mo sọ èyí fún yín, ẹ̀yin yóò jíyìn gbogbo ìsọkúsọ yín ní ọjọ́ ìdájọ́ Nítorí nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín ni a fi dá yin láre, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín sì ni a ó fi dá yin lẹ́bi Nígbà náà ni, díẹ̀ nínú àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin wí fún pé Olùkọ́, àwa fẹ́ rí iṣẹ́ àmì kan lọ́dọ̀ rẹ̀ Ó sì dá wọn lóhùn wí pé Ìran búburú àti ìran panságà ń béèrè àmì ṣùgbọ́n kò sí àmí tí a ó fi fún un, bí kò ṣe àmì Jónà wòlíì Bí Jónà ti gbé inú ẹja ńlá fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí Ọmọ Ènìyàn yóò gbé ní inú ilẹ̀ fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta Àwọn ará Nínéfè yóò dìde pẹ̀lú ìran yìí ní ọjọ́ ìdájọ́ Wọn yóò sì dá a lẹ́bi Nítorí pé wọ́n ronú pìwàdà nípa ìwàásù Jónà Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀ jù Jónà wà níhìn-in yìí Ọbabìnrin gúsù yóò sì dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ sí ìran yìí yóò sì dá a lẹ́bi nítorí tí ó wá láti ilẹ̀ ìkangun ayé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n láti ẹnu Sólóḿonì Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀ jù Sólómónì ń bẹ níhìn-ín yìí Nígbà tí ẹ̀mí búburú kan bá jáde lára ènìyàn, a máa rìn ní aṣálẹ̀, a máa wá ibi ìsinmi, kò sì ní rí i Nígbà náà ni ẹ̀mí yóò wí pé, Èmi yóò padà sí ara ọkùnrin tí èmí ti wá Bí ó bá sì padà, tí ó sì bá ọkàn ọkùnrin náà ni òfìfo, a gbà á mọ́, a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́ Nígbà náà ni ẹ̀mí ẹ̀ṣù náà yóò wá ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun lọ Gbogbo wọn yóò sì wá sí inú rẹ̀, wọn yóò máa gbé ibẹ̀ Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà a sì burú ju ti ìṣáájú lọ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí fún ìran búburú yìí pẹ̀lú Bí Jésù ti ṣe ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wà lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ Nígbà náà ni ẹnì kan wí fún un pé, Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró dè ọ́ lóde wọ́n ń fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀ Ó sì fún ni èsì pé, Ta ni ìyá mi Ta ni àwọn arákùnrin mi Ó nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí pé, Wò ó, ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni wọ̀nyí Nítorí náà, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi Òwe Afúnrúgbìn Ní ọjọ́ kan náà, Jésù kúrò ní ilé, ó jókòó sí etí òkun Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀-ojú omi, ó jókòó, gbogbo ènìyàn sì dúró létí òkun Nígbà náà ni ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe bá wọn sọ̀rọ̀, wí pé Àgbẹ̀ kan jáde lọ gbin irúgbìn sínú oko rẹ̀ Bí ó sì ti gbin irúgbìn náà, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì jẹ ẹ́ Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀ Àwọn irúgbìn náà sì dàgbà sókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn Ṣùgbọ́n nígbà tí òòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọ sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárin ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rún, òmiràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ó ti gbìn Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bí i pé, Èé ṣe tí ìwọ ń fi òwe bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ Ó sì da wọn lóhùn pé, Ẹ̀yin ni a ti fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wọn Ẹnikẹ́ni tí ó ní, òun ni a ó fún sí i, yóò sì ní lọ́pọ̀lọpọ̀ Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ ẹni tí kò ní, ni a ó ti gbà èyí kékeré tí ó ní náà Ìdí nì yìí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ Ní ti rírí, wọn kò rí ní ti gbígbọ́ wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yé wọn Sí ara wọn ni a ti mú àṣọtẹ́lẹ̀ wòlíì Àìsáyà ṣẹ  Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọn kì yóò sì yé yín ní rírí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́ etí wọn sì wúwo láti gbọ́ ojú wọn ni wọ́n sì dì nítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn rí kí wọ́n má ba à fi ètí wọn gbọ́ kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òge, kí wọn má ba à yí padà, kí èmi ba à le mú wọn lára dá Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ojú yín, nítorí wọ́n ríran, àti fún etí yín, nítorí ti wọ́n gbọ́ Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti ènìyàn Ọlọ́run ti fẹ́ rí ohun tí ẹ̀yin ti rí, ki wọ́n sì gbọ́ ohun tí ẹ ti gbọ́, ṣùgbọ́n kò ṣe é ṣe fún wọn Nítorí náà, ẹ fi etí sí ohun tí òwe afúnrúgbìn túmọ̀ sí Nigbà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìjọba ọ̀run ṣùgbọ́n tí kò yé e, lẹ́yìn náà èṣù á wá, a sì gba èyí tí a fún sí ọkàn rẹ̀ kúrò Èyí ni irúgbìn ti a fún sí ẹ̀bá ọ̀nà Ẹni tí ó sì gba irúgbìn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ orí àpáta, ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, lọ́gán, ó sì fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà Ṣùgbọ́n nítorí kò ní gbòǹgbò, ó wà fún ìgbà díẹ̀ nígbà tí wàhálà àti inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà ní ojú kan náà yóò sì kọsẹ̀ Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso rẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e òun sì so èṣo òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n Jésù tún pa òwe mìíràn fún wọn Ìjọba ọ̀run dàbí àgbẹ̀ kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀ Ṣùgbọ́n ní òru ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn, ọ̀ta rẹ̀ wá sí oko náà ó sì gbin èpò sáàrin àlìkámà, ó sì bá tirẹ̀ lọ Nígbà tí àlíkámà náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, tí ó sì so èso, nígbà náà ni èpò náà fi ara hàn Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ àgbẹ̀ náà wá, wọ́n sọ fún un pé, Ọ̀gá, irúgbìn rere kọ́ ni ìwọ ha gbìn sí oko rẹ nì Báwo ni èpò ṣe wà níbẹ̀ nígbà náà Ó sọ fún wọn pé, Ọ̀tá ni ó ṣe èyí Wọ́n tún bí i pé, Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ kí a tu èpò náà kúrò Ó dá wọn lóhùn pé, Rárá, nítorí bí ẹ̀yin bá ń tu èpò kúrò, ẹ ó tu àlìkámà dànù pẹ̀lú rẹ̀ Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì máa dàgbà pọ̀, títí di àsìkò ìkórè Èmi yóò sọ fún àwọn olùkórè náà láti kọ́kọ́ ṣa àwọn èpò kúrò kí wọ́n sì dì wọ́n ní ìtí, kí a sì sun wọn, kí wọ́n sì kó àlìkámà sínú àká mi   Jésù tún pa òwe mìíràn fún wọn Ìjọba ọ̀run dàbí èso hóró músítádì, èyí tí ọkùnrin kan mú tí ó gbìn sínú oko rẹ̀ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ èso tí ó kéré púpọ̀ láàrin èṣo rẹ̀, ṣíbẹ̀ ó wá di ohun ọ̀gbìn tí ó tóbi jọjọ Ó sì wá di igi tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì wá, wọ́n sì fi ẹ̀ka rẹ ṣe ìbùgbé Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn Ìjọba ọ̀run dàbí yíìsìtì tí obìnrin kan mú tí ó pò mọ́ ìyẹ̀fun púpọ̀ títí tí gbogbo rẹ fi di wíwú Òwe ni Jésù fi sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, òwe ni ó fi bá wọn sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ Kí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì sọ lé wá sí ìmúsẹ pé Èmi yóò ya ẹnu mi láti fi òwe sọ̀rọ̀ Èmi yóò sọ àwọn ohun tí ó farasin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá Lẹ́yìn náà ó sì fi ọ̀pọ̀ ènìyàn sílẹ̀ lóde, ó wọ ilé lọ Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn wí pé, Ṣàlàyé òwe èpò inú oko fún wa Ó sì dá wọn lóhùn pé, Ọmọ ènìyàn ni ẹni tí ó ń fúnrúgbìn rere Ayé ni oko náà irúgbìn rere ni àwọn ènìyàn ti ìjọba ọ̀run Èpò ni àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ti èṣù, ọ̀tá tí ó gbin àwọn èpò sáàrin àlìkámà ni èṣù Ìkórè ni òpin ayé, àwọn olùkórè sì ní àwọn ańgẹ́lì Gẹ́gẹ́ bí a ti kó èpò jọ, tí a sì sun ún nínú iná, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé Ọmọ Ènìyàn yóò ran àwọn ańgẹ́lì rẹ̀, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tó ń mú ni dẹ́sẹ̀ kúrò ní ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn búburú Wọn yóò sì sọ wọ́n sí inú iná ìléru, níbi ti ẹkún òun ìpayínkeke yóò gbé wà Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò máa ràn bí òòrùn ní ìjọba Baba wọn Ẹni tí ó bá létí, jẹ́ kí ó gbọ́ Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́ Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó ni iye lórí, ó lọ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀ láti le rà á Bákan náà, a sì tún lè fi ìjọba ọ̀run wé àwọ̀n kan tí a jù sínú odò, ó sì kó onírúurú ẹja Nígbà tí àwọ̀n náà sì kún, àwọn apẹja fà á sókè sí etí bèbè òkun, wọ́n jókòó, wọ́n sì ṣa àwọn èyí tí ó dára sínú apẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n da àwọn tí kò dára nù Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé Àwọn ańgẹ́lì yóò wá láti ya àwọn ènìyàn búburú kúrò lára àwọn olódodo, Wọn ó sì ju àwọn ènìyàn búburú sínú iná ìléru náà, ní ibi ti ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà Jésù bí wọn léèrè pé, Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí yé yín Wọ́n dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni, ó yé wa Ó wí fún wọn pé, Nítorí náà ni olúkúlùkù olùkọ́ òfin tí a ti kọ́ nípa ìjọba ọ̀run ṣe dàbí ọkùnrin kan tí í ṣe baálé ilé, tí ó mú ìṣúra tuntun àti èyí tí ó ti gbó jáde láti inú yàrá ìṣúra rẹ̀ Lẹ́yìn ti Jésù ti parí òwe wọ̀nyí, ó ti ibẹ̀ kúrò lọ Ó wá sí ìlú òun tìkára rẹ̀, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú Ṣínágọ́gù, ẹnu sì yà wọ́n Wọ́n béèrè pé, Níbo ni ọkùnrin yìí ti mú ọgbọ́n yìí àti iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí wá Kì í há ṣe ọmọ gbẹ́nàgbẹ́nà ni èyí bí Ìyá rẹ̀ há kọ́ ni à ń pè ní Màríà bí Arákùnrin rẹ̀ ha kọ́ ni Jémísì, Jósẹ́fù, Símonì àti Júdásì bí Àwọn arábìnrin rẹ̀ gbogbo ha kọ́ ni ó ń bá wa gbé níhìn-ín yìí, nígbà náà níbo ni ọkùnrin yìí ti rí àwọn nǹkan wọ̀nyí Inú bí wọn sí i Ṣùgbọ́n Jésù wí fún wọn pé, Wòlíì a máa lọ́lá ní ibòmíràn, àfi ní ilé ara rẹ̀ àti ní ìlú ara rẹ̀ nìkan ni wòlíì kò ti lọ́lá Nítorí náà kò se iṣẹ́ ìyanu kankan níbẹ̀, nítorí àìnígbàgbọ́ wọn A bẹ́ Jòhánù Onítẹ̀bọmi lórí Ní àkókò náà ni Hẹ́rọ́dù ọba Tẹ́tírákì gbọ́ nípa òkìkí Jésù, ó wí fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Dájúdájú Jòhánù onítẹ́bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí Nísìnsin yìí Hẹ́rọ́dù ti mú Jòhánù, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Hẹ́rọ́díà aya Fílípì arákùnrin rẹ̀, nítorí Jòhánù onítẹ̀bọmi ti sọ fún Hẹ́rọ́dù pé, Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà Hẹ́rọ́dù fẹ pa Jòhánù, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù àwọn ènìyàn nítorí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé wòlíì ni Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù, ọmọ Hẹ́rọ́díà obìnrin jó dáadáa, ó sì tẹ́ Hẹ́rọ́dù lọ́run gidigidi Nítorí náà, Hẹ́rọ́dù jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, Fún mi ni orí Jòhánù onítẹ̀bọmi nínú àwo pọ̀kọ́ Inú ọba bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀jẹ́ rẹ̀ àti kí ojú má ba à tì í níwájú àwọn àlejò tó wà ba jẹ àsè, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́ Nítorí náà, a bẹ́ orí Jòhánù onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú A sì gbé orí rẹ̀ jáde láti fi fún ọmọbìnrin náà nínú àwo pọ̀kọ́, òun sì gbà á, ó gbé etọ ìyá rẹ̀ lọ Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù wá gba òkú rẹ̀, wọ́n sì sin ín Wọ́n sì wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jésù Nígbà tí Jésù gbọ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kúrò níbẹ̀, ó bá ọkọ̀ ojú-omi lọ sí ibi kọ́lọ́fin kan ní èbúté láti dá wà níbẹ̀ Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn si fi ẹṣẹ̀ rìn tẹ̀lé e láti ọ̀pọ̀ ìlú wọn Nígbà ti Jésù gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ò sì mú àwọn aláìsàn láradá Nígbà ti ilẹ̀ ń sú lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé, Ibi yìí jìnnà sí ìlú ilẹ̀ sì ń ṣú lọ Rán àwọn ènìyàn lọ sí àwọn ìletò kí wọ́n lè ra oúnjẹ jẹ Ṣùgbọ́n Jésù fèsì pé, Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò Ẹ fún wọn ní oúnjẹ Wọ́n sì da lóhùn pé, Àwá kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín Ó wí pé, Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-un àti ẹja méjì Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹẹ́dọ́gbọ̀n ọkùnrin, Láì ka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé Lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdì kejì Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnra rẹ̀ láti lọ gba àdúrà Nígbà tí ilẹ̀ sú, óun wà ni nìkan níbẹ̀, ní àkókò yìí ọkọ ojú-omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn Ní déédé agogo mẹ́rin òwúrọ̀, Jésù tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé iwin ni wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù Lójú kan náà, Jésù wí fún wọn pé, Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù Pétérù sì ké sí i pé, Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi Jésù dá a lóhùn pé, Ó dára, máa bọ̀ wá Nígbà náà ni Pétérù sọ̀ kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jésù Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì Ó kígbe lóhùn rara pé, Gbà mí, Olúwa Lójú kan náà, Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó dì í mú, ó sì gbà á Ó sì wí fún un pé, Èé ṣe tí ìwọ fi ṣiyè méjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́ Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà forí balẹ̀ fún un wọ́n wí pé, nítòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe Nígbà tí wọn ré kọjá sí apá kejì wọ́n gúnlẹ̀ sí Gẹ́nẹ́sárẹ́tì Nígbà ti wọn mọ̀ pé Jésù ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn Ohun mímọ́ àti ohun àìmọ́ Nígbà náà ní àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin tọ Jésù wá láti Jerúsálémù, wọn béèrè pé, Èé se tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ fi ń ṣe àìgbọ́ràn sí àwọn àṣà àtayébáyé Júù Nítorí tí wọn kò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun! Jésù sì dá wọn lóhùn pé, È é ha ṣe tí ẹ̀yin fi rú òfin Ọlọ́run, nítorí àṣà yín Nítorí Ọlọ́run wí pé, Bọ̀wọ̀ fún Baba òun ìyá rẹ, àtipé, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí baba tàbí ìyá rẹ̀, ní láti kú Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé, Ẹ̀bun fún Ọlọ́run i ohunkóhun tí ìwọ ìbá fi jèrè lára mi tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ó bọ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ ofin di asan nípa àṣà yín Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé  Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi Lásán ni ìsìn wọn nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyan kọ́ ni ní ẹ̀kọ́   Jésù pe ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ó wí pé, Ẹ tẹ́tí, ẹ sì jẹ́ kí nǹkan tí mo sọ yé yín Ènìyàn kò di aláìmọ́ nípa ohun tí ó wọ ẹnu ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti ẹnu jáde wá ni ó sọ ni di aláìmọ́   Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, Ǹjẹ́ ìwọ mọ̀ pé inú bí àwọn Farisí lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó sọ yìí Jésù dá wọn lóhùn pé, Gbogbo igi tí Baba mi ti ń bẹ ni ọ̀run kò bá gbìn ni á ó fà tu ti gbòǹgbò ti gbòǹgbò, Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n Bí afọ́jú bá sì ń fi ọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò jìn sí kòtò Pétérù wí, Ṣe àlàyé òwe yìí fún wa Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Èé ha ṣe tí ìwọ fi jẹ́ aláìmòye síbẹ̀ Ìwọ kò mọ̀ pé ohunkóhun tí ó gba ẹnu wọlé, yóò gba ti ọ̀nà oúnjẹ lọ, a yóò sì yà á jáde Ṣùgbọ́n ohun tí a ń sọ jáde láti ẹnu, inú ọkàn ni ó ti ń wá, èyí sì ni ó ń sọ ènìyàn di aláìmọ́ Ṣùgbọ́n láti ọkàn ni èrò búburú ti wá, bí ìpanìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, irọ́ àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ Àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí ni ó ń sọ ènìyàn di aláìmọ́ Ṣùgbọ́n láti jẹun láì wẹ ọwọ́, kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́   Jésù sì ti ibẹ̀ kúrò lọ sí Tírè àti Sídónì Obìnrin kan láti Kénánì, tí ó ń gbé ibẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ Ó ń bẹ̀bẹ̀, ó sì kígbe pé, Olúwa, ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi ọmọbìnrin mi ní ẹ̀mí èṣù ti ń dá a lóró gidigidi Ṣùgbọ́n Jésù kò fún un ní ìdáhùn, Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á nìyànjú pé, lé obìnrin náà lọ, nítorí ó ń kígbe tọ̀ wá lẹ́yìn Ó dáhùn pé, Àgùntàn ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí ó nù nìkan ni a rán mi sí Obìnrin náà wá, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ sí i pé, Olúwa ṣàánú fún mi Ó sì dáhùn wí pé, Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá Obìnrin náà sì wí pé, Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ajá a máa jẹ èérún tí ó ti orí tábìlì olówó wọn bọ́ sílẹ̀ Jésù sì sọ fún obìnrin náà pé, Ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ! A sì ti dáhùn ìbéèrè rẹ A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ lára dá ní wákàtí kan náà Jésù ti ibẹ̀ lọ sí òkun Gálílì Ó gun orí òkè, o sì jókòó níbẹ̀ Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, àti àwọn arọ, afọ́jú, amúkùn-ún, odi àti ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jésù Òun sì mú gbogbo wọn lárada Ẹnú ya ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n rí àwọn odi tó ń sọ̀rọ̀, amúkùn-ún tó di alára pípé, arọ tí ó ń rìn àti àwọn afọ́jú tí ó ríran Wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó wí pé, Àánú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí nítorí wọ́n ti wà níhìn-ín pẹ̀lú mi fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko báyìí Wọn kò sì tún ní oúnjẹ mọ́ Èmi kò fẹ́ kí wọn padà lébi, nítorí òyì lè kọ́ wọn lójú ọ̀nà Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì dá a lóhùn pé, Níbo ni àwa yóò ti rí oúnjẹ ní ihà níhìn-ín yìí láti fi bọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí Jésù sì béèrè pé, ìsù Búrẹ́dì mélòó ni ẹ̀yín ní Wọ́n sì dáhùn pé, Àwa ní ìsù àkàrà méje pẹ̀lú àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ Jésù sì sọ fún gbogbo ènìyàn kí wọn jókòó lórí ilẹ̀ Òun sì mú ìsù àkàrà méje náà àti ẹja náà Ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, ó bù wọ́n sì wẹ́wẹ́, ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Wọ́n sì pín in fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà Gbogbo wọn jẹ, wọ́n sì yó Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì sa èyí tókù, ẹ̀kún agbọ̀n méje ni èyí tó sẹ́kù jẹ́ Gbogbo wọn sì jẹ́ ẹgbàají ọkùnrin láì kan àwọn obìnrin àti ọmọdé Lẹ́yìn náà, Jésù rán àwọn ènìyàn náà lọ sí ilé wọn, ó sì bọ́ sínú ọkọ̀, ó ré kọjá sí Mágádánì Bíbéèrè Fún Àmì Àwọn Farisí àti àwọn Sadusí wá láti dán Jésù wò Wọ́n ní kí ó fi àmì ńlá kan hàn àwọn ní ojú ọ̀run Ó dá wọn lóhùn pé, Nígbà tí ó bá di àṣálẹ́, ẹ ó sọ pé, Ìbá dára kí ojú ọ̀run pọ́n Ní òwúrọ̀, Èyin yóò wí pé ọjọ́ kì yóò dára lónìí, nítorí ti ojú ọ̀run pọ́n, ó sì ṣú dẹ̀dẹ̀, ẹ̀yin àgàbàgebè, ẹ̀yin le sọ àmì ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò le mọ àmì àwọn àkókò wọ̀nyí Ìran búburú aláìgbàgbọ́ yìí ń béèrè àmì àjèjì mélòó kàn ni ojú sánmọ̀, ṣùgbọ́n a kí yóò fún ẹnìkan kan ní àmì bí kò ṣe àmì Jónà Nígbà náà ni Jésù fi wọ́n sílẹ̀, ó sì bá tirẹ̀ lọ Nígbà tí wọ́n dé apá kejì adágún, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sàkíyèsí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà kankan lọ́wọ́ Jésù sì kìlọ̀ fún wọn pé, Ẹ kíyè sára, ẹ sì ṣọ́ra, ní ti ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí Wọ́n ń sọ eléyìí ni àárin ara wọn nítorí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà lọ́wọ́ Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èé ṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́ Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsìn yìí Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹẹ́dọ́gbọ́n ènìyàn pẹ̀lú ìsù búrẹ́dì márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kó jọ bí àjẹkù Ẹ kò sì tún rántí ìsù méje tí mo fi bọ́ ẹgbààjì ènìyàn àti iye àjẹkù tí ẹ kó jọ È é ha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti búrẹ́dì Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ti Sadusí Nígbà náà ni ó ṣẹ̀sẹ̀ wá yé wọn pé, kì í ṣe nípa ti ìwúkàrà ní ó sọ wí pé kí wọ́n kíyè sára, bí kò se tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti Sadusí Nígbà tí Jésù sì dé Kesaríà-Fílípì, ó bi àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ pé, Ta ni àwọn ènìyàn ń fi Ọmọ ènìyàn pè Wọ́n dá a lóhùn pé, Àwọn kan ni Jòhánù onítẹ̀bọ́mì ni, àwọn mìíràn wí pé, Èlíjà ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremáyà ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì Ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ Ó bi í léèrè pé, Ta ni ìwọ rò pé mo jẹ́ Símónì Pétérù dáhùn pé, Ìwọ ni Kírísítì náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè Jésù sì wí fún un pé, Alábùnkún-fún ni ìwọ Símónì ọmọ Jónà, nítorí ènìyàn kọ́ ló fi èyí hàn bí kò se Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Pétérù àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò-òkú kì yóò lè borí rẹ̀ Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run Ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run Ohunkóhùn tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run Nígbà náà kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Òun ni Kírísítì náà Láti ìgbà yìí lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí iṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ kedere nípa lílọ sí Jerúsálémù láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyà lọ́wọ́ àwọn, olórí àwọn àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin, pé wọn yóò pa òun, àti pé òun yóò jí dìde sí ààyè ní ọjọ́ kẹ́ta Pétérù mú Jésù sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí pé, Kí a má rí i Olúwa Èyí kì yóò ṣẹlẹ̀ sí Ọ Jésù pa ojú dà, ó sì wí fún Pétérú pé, Kúrò lẹ́yìn mi, Sàtáni! Ohun ìkọ̀ṣẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi ìwọ kò ro ohun tí i se ti Ọlọ́run, bí kò se èyí ti se ti ènìyàn Nígbà náà ni Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóò sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, yóò rí i Èrè kí ni ó jẹ́ fún ènìyàn bí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi dípò ẹ̀mí rẹ̀ Nítorí Ọmọ ènìyàn yóò wá nínú ogo baba rẹ pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì rẹ̀, nígbà náà ni yóò sì san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ Lóòótọ́ ni mo wí fún yín Ẹlòmíràn wà nínú àwọn tí ó níhìn-ín yìí, tí kì yóò ri ikú títí wọn ó fi rí ọmọ-ènìyàn tí yóò máa bà ní ìjọba rẹ̀ Orí Òkè Ìparadà Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Jésù mú Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ Jákọ́bù, ó mú wọn lọ sí orí òkè gíga kan tí ó dá dúró Níbẹ̀ ara rẹ̀ yí padà níwájú wọn Ojú rẹ̀ sì ràn bí oòrùn, aṣọ rẹ̀ sì funfun bí ìmọ́lẹ̀ Lójijì, Mósè àti Èlíjà fara hàn, wọ́n sì ń bá Jésù sọ̀rọ̀ Pétérù sọ fún Jésù pé, Olúwa, jẹ́ kí a kúkú máa gbé níhìn-ín yìí Bí ìwọ bá fẹ́, èmi yóò pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè, àti ọ̀kan fún Èlíjà Bí Pétérù ti sọ̀rọ̀ tán, àwọ̀sánmọ̀ dídán síji bò wọ́n, láti inú rẹ̀ ohùn kan wí pé, Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni ti inú mi dùn sí gidigidi Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀! Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbọ́ èyí, wọ́n dojú bolẹ̀ Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi Ṣùgbọ́n Jésù sì tọ̀ wọ́n wá Ó fi ọwọ́ kàn wọ́n, ó wí pé, Ẹ dìde, ẹ má ṣe bẹ̀rù Nígbà tí wọ́n sì gbé ojú wọn sókè, tí wọ́n sì wò ó, Jésù nìkan ni wọn rí Bí wọ́n sì ti ń sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè, Jésù pàṣẹ fún wọn pé Ẹ kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni ohun tí ẹ rí, títí ọmọ-ènìyàn yóò fi jí dìde kúrò nínú òkú Àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ́ pé, Kí ni ó fà á tí àwọn olùkọ́ òfin fi ń wí pé, Èlíjà ní láti kọ́ padà wá Jésù sì dáhùn pé, Dájúdájú òtítọ́ ni wọ́n ń sọ Èlíjà wá láti fi gbogbo nǹkan sí ipò Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́ Èlíjà ti dé Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i Bákan náà, Ọmọ ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ̀ pé ó n sọ̀rọ̀ nípa Jòhánù onítẹ̀bọmi fún wọn ni Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ ìjọ ènìyàn, ọkùnrin kan tọ̀ Jésù wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí pé, Olúwa, ṣàánú fún ọmọ mi, nítorí tí ó ní wárápá Ó sì ń joró gidigidi, nígbà púpọ̀ ni ó máa ń ṣubu sínú iná tàbí sínú omi Mo sì ti mú un tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn Jésù sì dáhùn wí pé, A! ẹ̀yìn alágídí ọkàn àti aláìgbàgbọ́ ènìyàn, èmi yóò ti bá yín gbé pẹ́ tó Èmi ó sì ti fara dà á fún yín tó Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín yìí Nígbà náà ni Jésù bá ẹ̀mí èṣù tí ó ń bẹ nínú ọmọkùnrin náà wí, ó sì fi í sílẹ̀, à mú ọmọkùnrin náà láradá láti ìgbà náà lọ Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi Jésù níkọ̀kọ̀ pé, È é ṣe tí àwa kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde Jésù sọ fún wọn pé, Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré Lóòòtọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí músítadì, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, Ṣípò kúrò níhìn-ín yìí òun yóò sì sí ipò Kò sì nií sí ohun tí kò níí ṣe é ṣe fún yín Ṣùgbọ́n irú ẹ̀mí èṣù yìí kò ní lọ, bí kò ṣe nípa ààwẹ̀ àti àdúrà Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní Gálílì, Jésù sọ fún wọn pé, Láìpẹ́ yìí a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ Wọn yóò sì pa á, ní ọjọ́ kẹ́ta lẹ́yìn èyí, yóò sì jí dìde sí ìyè Ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi Nígbà tí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé Kápánámù, àwọn agbowó-òde tọ Pétérù wá wọ́n sì bí i pé, Ǹjẹ́ Olúwa yín ń dá owó tẹ̀ḿpìlì Pétérù sì dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san Nígbà tí Pétérù wọ ilé láti bá Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Jésù ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, Jésù bí i pé, Kí ni ìwọ rò, Símónì Ǹjẹ́ àwọn ọba ń gba owó-orí lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí lọ́wọ́ àwọn àlejò Pétérù dáhùn pé, Lọ́wọ́ àwọn àlejò ni Jésù sì tún wí pé, Èyí jẹ́ wí pé àwọn ọmọ onílẹ̀ kì í san owó-òde Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, àwa kò fẹ́ mú wọn bínú Nítorí náà, ẹ lọ sí etí òkun, kí ẹ sì sọ ìwọ̀ sí omi Ẹ mú ẹja àkọ́kọ́ tí ẹ kọ́ fà sókè, ẹ ya ẹnu rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì rí owó idẹ kan níbẹ̀, ki ẹ fi fún wọn fún owó-orí tèmi àti tirẹ̀ Ẹni tí ó Tóbi jù Ní Ìjọba Ọ̀run Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í léèrè pé, Ta ni ẹni ti ó tóbi jùlọ ní ìjọba ọ̀run Jésù sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ Ó sì mú un dúró láàrin wọn Ó wí pé, Lóòtọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run Àti pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọ kékeré bí èyí nítorí orúkọ mi, gbà mí Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọkékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ sìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi òkun Ègbé ni fún ayé nítorí gbogbo ohun ìkọ̀sẹ̀ rẹ̀! Ohun ìkọ̀sẹ̀ kò le ṣe kó má wà, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípaṣẹ̀ ẹni tí ìkọ̀sẹ̀ náà ti wá! Nítorí náà, bí ọwọ́ tàbí ẹṣẹ̀ rẹ yóò bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀, gé e kúrò, kí o sì jù ú nù Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run ní akéwọ́ tàbí akésẹ̀ ju pé kí o ni ọwọ́ méjì àti ẹsẹ̀ méjì ki a sì sọ ọ́ sínú iná ayérayé Bí ojú rẹ yóò bá sì mú kí o dẹ́sẹ̀, yọ ọ́ kúrò kí ó sì sọ ọ́ nù Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run pẹ̀lú ojú kan, ju pé kí o ní ojú méjì, kí a sì jù ọ́ sí iná ọ̀run àpádì Ẹ rí i pé ẹ kò fi ojú bẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, nígbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run ń láti lọ wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn wá láti gba àwọn tí ó nù là Kí ni ẹ̀yin rò Bí ọkùnrin kan bá ni ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ẹyọ kan nínú wọn sì sọnù, ṣé òun kì yóò fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún ìyókù sílẹ̀ sórí òkè láti lọ wá ẹyọ kan tó nù náà bí Ǹjẹ́ bí òun bá sì wá á rí i, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé inú rẹ̀ yóò dùn nítorí rẹ̀ ju àwọn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún tí kò nù lọ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ni kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, pé ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kí ó ṣègbé Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ ní ìkọ̀kọ̀ kí o sì sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un Bí ó bá gbọ̀ tìrẹ, ìwọ ti mú arákùnrin kan bọ̀ sí ipò Ṣùgbọ́n bí òun kò bá tẹ́tí sí ọ, nígbà náà mú ẹnìkan tàbí ẹni méjì pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì tún padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ọ̀rọ̀ náà bá le fi ìdí múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta náà Bí òun bá sì tún kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn, nígbà náà sọ fún ìjọ ènìyàn Ọlọ́run Bí o bá kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọ́run, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ tàbí agbowó-òde Àti pé mo tún sọ èyí fún yín, Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá dè ní ayé, ni a dè ní ọ̀run Ohunkóhùn ti ẹ̀yin bá sì ti tú ni ayé, á ò tú u ní ọ̀run Mo tún sọ èyí fún yín, bí ẹ̀yin méjì bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé yìí, nípa ohunkóhun tí ẹ béèrè, Baba mi ti ń bẹ ní ọ̀run yóò sì ṣe é fún yín Nítorí níbi ti ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta bá kó ara jọ ni orúkọ mi, èmi yóò wà láàrin wọn níbẹ̀ Nígbà náà ni Pétérù wá sọ́dọ̀ Jésù, ó béèrè pé, Olúwa, nígbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mi, tí èmi yóò sì dáríjì í Tàbí ní ìgbà méje ni Jésù dáhùn pé, Mo wí fún ọ, kì í se ìgbà méje, ṣùgbọ́n ní ìgbà àádọ́rin méje Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ se ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbésè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàáárún talẹ́ńtì Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà Nígbà náà ni ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ Nígbà náà, ni olúwa ọmọ-ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbésè náà jì í Ṣùgbọ́n bí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún dínárì, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé san gbéṣè tí o jẹ mí lójú ẹṣẹ̀ Arákùnrin náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbésè náà tán pátápátá Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó sẹlẹ̀ Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, Ìwọ Ọmọ-ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbésè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi Kò ha ṣe ẹ̀tọ́ fún ọ láti ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣáànú fún ọ Ní ibínú, olówó rẹ̀ fi í lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ láti fi ìyà jẹ ẹ́, títí tí yóò fi san gbogbo gbésè èyí ti ó jẹ ẹ́ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run yóò sí ṣe sì ẹnì kọ̀ọ̀kan, bí ẹ̀yin kò bá fi tọkàntọkàn dárí ji àwọn arákùnrin yín Ìkọsílẹ̀ Lẹ́yìn tí Jésù ti parí ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò ní Gálílì Ó sì yípo padà sí Jùdíà, ó gba ìhà kejì odò Jọ́dánì Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú wọn láradá níbẹ̀ Àwọn Farisí wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti dán an wò Wọ́n bi í pé, Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ohunkóhun Ó dáhùn pé, A ti rí i kà pé ní ìpilẹ̀sẹ, Ọlọ́run dá wọn ni ọkùnrin àti obìnrin Ó sì wí fún un pé, Nítorí ìdí èyí Ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sí da ara pọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì náà á sì di ara kan Wọn kì í tún ṣe méjì mọ́, ṣùgbọ́n ara kan Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run bá ti so ṣọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà wọ́n Wọ́n bi í pé Kí ni ìdí tí Mósè fi pàṣẹ pé, ọkùnrin kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nípa fífún un ní ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ Jésù dáhùn pé, Mósè yọ̀ǹda kí ẹ kọ aya yín sílẹ̀ nítorí ọkàn yín le Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ láti àtètèkọ́ṣe Mo sọ èyí fún yín pé, ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, tí ó sì fẹ́ òmíràn, ó ṣe panṣágà Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, Bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí láàrin ọkọ àti aya, kó ṣààfààní fún wa láti gbé ìyàwó J ésù dáhùn pé, Gbogbo ènìyàn kọ́ ló lé gba ọ̀rọ̀ yìí, bí kò ṣe iye àwọn tí a ti fún Àwọn mìíràn jẹ́ akúra nítorí bẹ́ẹ̀ nía bí wọn, àwọn mìíràn ń bẹ tí ènìyàn sọ wọn di bẹ́ẹ̀ àwọn mìíràn kọ̀ láti gbé ìyàwó nítorí ìjọba ọ̀run Ẹni tí ó bá lè gbà á kí ó gbà á Lẹ́yìn náà a sì gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ wá sọ́dọ̀ Jésù, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì gbàdúrà fún wọn Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn pé, Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun, nítorí irú wọn ni ìjọba ọ̀run Lẹ́yìn náà, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀ Ẹnì kan sì wá ó bí Jésù pé, Olùkọ́, ohun rere wo ni èmi yóò ṣe kí n tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun Jésù dá a lóhùn pé, È é ṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe Ẹni rere Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́ Ọkùnrin náà béèrè pé, Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí Jésù dáhùn pé,  Má ṣe pànìyàn, má ṣe ṣe panṣágà, má ṣe jalè, má ṣe ìjẹ̀rìí èké, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ Kí o sì fẹ́ aládúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi mo ní láti ṣe Jésù wí fún un pé, Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀ Nígbà náà, ní Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run Mo tún wí fún yín pé, Ó rọrùn fún ràkúnmí láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ èyí, ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n béèrè pé, Ǹjẹ́ ta ni ó ha le là Jésù sì tẹjú mọ́ wọn, ó wí pé, Bí o bá jẹ́ ti ènìyàn ni, eléyìí sòro Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ti Ọlọ́run ni, ohun gbogbo ni ṣíṣe Pétérù sì wí fún un pé, Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀lé Ọ Kí ni yóò jẹ́ èrè wa Jésù dáhùn pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, Nígbà ìsọdọ̀tun ohun gbogbo, nígbà tí Ọmọ-Ènìyàn yóò jókòó lórí ìtẹ̀ tí ó lógo, dájúdájú, ẹ̀yin ọmọ-ẹ̀yìn mi yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ méjìlá láti ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ilé tàbí arákùnrin tàbí arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ, tàbí ohun ìní rẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mí, yóò gba ọgọọgọ́rùn-ún èrè rẹ̀ láyé, wọn ó sì tún jogún ìyè àìnípẹ̀kun Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ṣíwájú nísinsìn yìí ni yóò kẹ́yìn, àwọn tí ó kẹ́yìn ni yóò sì ṣíwájú Ìbẹ̀wò àwọn Amòye Lẹ́yìn ìgbà tí a bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà, ni àkókò ọba Hẹ́rọ́dù, àwọn amoye ti ìlà-oòrùn wá sí Jerúsálémù Wọ́n si béèrè pé, Níbo ni ẹni náà tí a bí tí í ṣe ọba àwọn Júù wà Àwa ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà-oòrun, a sì wá láti foríbalẹ̀ fún un Nígbà tí ọba Hẹ́rọ́dù sì gbọ́ èyí, ìdáàmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerúsálémù pẹ̀lú rẹ̀ Nígbà tí ó sì pe àwọn olórí àlùfàá àti àwọn olùkọ́ òfin jọ, ó bi wọ́n léèrè níbi ti a ó gbé bí Kírísítì Wọ́n sì wí pé, Ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà, èyí ni ohun tí wòlíì ti kọ ìwé rẹ̀ pé  Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ní ilẹ̀ Jùdíà, ìwọ kò kéré jù láàrin àwọn ọmọ aládé Jùdíà nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde, Ẹni ti yóò ṣe àkóso lórí Ísírẹ́lì, àwọn ènìyàn mi   Nígbà náà ni Hérọ́dù ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan-an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀ Ó sì rán wọn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó sì wí pé, Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínnífínní ní ti ọmọ náà tí a bí Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títítí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà Nígbà tí wọ́n sì rí ìràwọ̀ náà, ayọ̀ kún ọkàn wọn Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n forí balẹ̀ fún un Nígbà náà ni wọ́n tú ẹrù wọn, wọ́n sì ta Jésù lọ́rẹ wúrà, tùràrí àti òjíà Nítorí pé Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wọn ní ojú àlá pé kí wọ́n má ṣe padà tọ Hérọ́dù lọ mọ́, wọ́n gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ìlú wọn Nígbà tí wọn ti lọ, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Jósẹ́fù ní ojú àlá pé, Dìde, gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sá lọ sí Éjíbítì Dúró níbẹ̀ títítí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Hẹ́rọ̀dù yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ-ọwọ́ náà Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Éjíbítì, ó sì wà níbẹ̀ títítí Hẹ́rọ́dù fi kú Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àṣọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé Mo pe ọmọ mi jáde láti Éjíbítì wá Nígbà tí Hẹ́rọ̀dù rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà Nígbà náà ni èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeriemáyà wá sẹ pé A gbọ́ ohùn kan ní Rámà, Ohùn réré ẹkún àti ọ̀fọ̀ ńlá Rákélì ń sọkùn àwọn ọmọ rẹ̀ Ó kọ̀ láti gbìpẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́ Lẹ́yìn ikú Hẹ́rọ́dù, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Jósẹ́fù lójú àlá ní Éjíbítì Ó sì wí fún un pé, Dìde gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ padà sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí àwọn tí ń wá ọmọ-ọwọ́ náà láti pa ti kú Nítorí náà, Ó sì dìde, ó gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ó sì wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n nígbà tí ó gbọ́ pé Ákílọ́sì ni ó ń jọba ní Jùdíà ní ipò Hẹ́rọ́dù baba rẹ̀, ó bẹ̀rù láti lọ sí ì bẹ̀ Nítorí tí Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún un ní ojú àlá, ó yí padà, ó sì gba ẹkùn Gálílì lọ, ó sì lọ í gbé ní ìlú tí a pè ní Násárẹ́tì Nígbà náà ni èyí tí a sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì wá sí ìmúṣẹ A ó pè é ní ará Násárẹ́tì Òwe Àwọn Òṣìṣẹ́ Nínú Ọgbà Àjàrà Nítorí ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin tí ó jẹ́ baálé kan, tí ó jí jáde lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí ó gba àwọn alágbàṣe sínú ọgbà àjàrà rẹ̀ Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀ Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà Ó wí fún wọn pé, Ẹ̀yin pàápàá, ẹ lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi, bí ó bá sì di òpin ọjọ́, èmi yóò san iye ti ó bá yẹ fún yín Wọ́n sì lọ Ó tún jáde lọ́sàn-án ní nǹkan bí wákàtí kẹfa àti wákàtí kẹṣàn-án, ó tún ṣe bákan náà Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárin ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró Ó bi wọ́n pé, È é ṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́ Wọ́n sì dáhùn pé, Nítorí pé kò sí ẹni tí yóò fún wa ní iṣẹ́ ṣe Ó tún sọ fún wọn pé, Ẹ̀yin náà ẹ jáde lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú nínú ọgbà àjàrà mi Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà sọ fún aṣojú rẹ̀ pé, Pe àwọn òsiṣẹ́ náà, kí ó san owó iṣẹ́ wọn fún wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ìkẹyìn lọ sí ti ìṣáájú Nígbà tí àwọn ti a pè ní wákàtí kọkànlá ọjọ́ dé, ẹnì kọ̀ọ̀kan gba owó dínárì kan Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣíṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó ti wọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan Bí wọ́n ti ń gbà á, wọ́n ń kùn sí onílẹ̀ náà, Pé, Wákàtí kan péré ni àwọn tí a gbà kẹ́yìn fi ṣiṣẹ́, ìwọ sì san iye kan náà fún wọn àti àwa náà ti a fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ nínú oòrùn gan-gan Ṣùgbọ́n ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, Ọ̀rẹ́, kò sí aburú nínú nǹkan tí èmi ṣe sí yín Kì í ha ṣe pé ẹ̀yin gbà láti ṣiṣẹ́ fún owó dínárì kan Ó ní, Gba èyí tíí ṣé tìrẹ, ki ó sì máa lọ Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bí mo ti fi fún ọ Àbí ó lòdì sí òfin pé kí èmi fún ẹnikẹ́ni ní owó mi bí mo bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀ Kí ni ìdí tí ìwọ ní láti bínú nítorí èmi ṣe ohun rere Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ìkẹyìn yóò di ẹni ìṣáájú, ẹni ìṣáájú yóò sì di ẹni ìkẹyìn Bí Jésù ti ń gòkè lọ sí Jerúsálémù, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé, Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú Wọn yóò sì lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti nàa án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sébédè bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jésù, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojú rere rẹ̀ Jésù béèrè pé, Kí ni ìwọ ń fẹ́ Ó sì dáhùn pé, Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn ó sì wí pé, Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀yin ń béèrè, ẹ̀yin ha le mu nínú aago tí èmi ó mu Wọ́n dáhùn pé, Àwa lè mu ún Jésù sì wí fún wọn pé, Dájúdájú, ẹ̀yin yóò mu nínú aago mi, ṣùgbọ́n èmi kò ní àṣẹ láti sọ irú ènìyàn tí yóò jòkòó ní apá ọ̀tún tàbí apá òsì Baba mi ti pèsè àyè wọ́n-ọn-nì sílẹ̀ fún kìkì àwọn tí ó yàn Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàà ìyókù sì gbọ́ èyí, wọ́n bínú sí àwọn arákùnrin méjì yìí Ṣùgbọ́n Jésù pé wọ́n papọ̀, ó wí pé, Dájúdájú, ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ọba aláìkọlà a máa lo agbára lórí wọn, àwọn ẹni ńlá láàrin wọn a sì máa fi ọlá tẹrí àwọn tí ó wà lábẹ́ wọn ba Ṣùgbọ́n èyí yàtọ̀ láàrin yín Dípò bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá ń fẹ́ ṣe olórí láàrin yín, ní láti ṣe bí ìránṣẹ́ fún yín ni, Àti ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe olórí nínú yín, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣe Ọmọ-ọ̀dọ̀ yin Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-Ènìyàn kò ṣe wá sí ayé, kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún yín, àti láti fi ẹ̀mí rẹ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn Bí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń fi ìlú Jẹ́ríkò sílẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì wọ́ tẹ̀lé e lẹ́yìn Àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì sì jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, nígbà tí wọ́n sí gbọ́ pé Jésù ń kọjá lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí kígbe pé, Olúwa, Ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún wa! Àwọn ènìyàn sí bá wọn wí pé kí wọn dákẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n kígbe sóke sí i Olúwa, ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún wa! Jésù dúró lójú ọ̀nà, ó sì pè wọ́n pé, Ó béèrè pé, Kí ni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ṣe fún yín Wọ́n dáhùn pé, Olúwa, àwa fẹ́ kí a ríran Àánú wọn sì ṣe Jésù, ó fi ọwọ́ kan ojú wọn Lójú kan náà, wọ́n sì ríran, wọ́n sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Fífi Ayọ̀ Wọlé Bí wọ́n ti sún mọ́ Jérúsalẹmu, tí wọ́n dé ìtòòsí ìlú Bẹ́tífágè ní orí òkè Ólífì, Jésù sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì, Ó wí fún wọn pé, Ẹ lọ sí ìletò tó wà ni tòòsí yín, ẹ̀yin yóò rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ti wọ́n so pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi Bí ẹnikẹ́ni bá sì béèrè ìdí tí ẹ fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sáà wí pé, Olúwa ní wọn-ọ́n lò, òun yóò sì rán wọn lọ Èyí ṣẹlẹ̀ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì ṣẹ pé Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Síónì pé, Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́   Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sí lọ, wọ́n ṣe bí Jésù ti sọ fún wọn Wọ́n sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, wọ́n tẹ́ aṣọ lé e, Jésù si jókòó lórí rẹ̀ Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn sẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé, Hòsánà fún ọmọ Dáfídì! Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa! Hòsánà ní ibi gíga jùlọ! Bí Jésù sì ti ń wọ Jerúsálémù, gbogbo ìlú mì tìtì, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wọn pé, Ta nì yìí Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì dáhùn pé, Èyí ni Jésù, wòlíì náà láti Násárẹ́tì ti Gálílì Jésù sì wọ inú tẹ́ḿpì Ọlọ́run Ó sì lé àwọn ti ń tà àti àwọn ń rà níbẹ̀ jáde Ó yí tábìlì àwọn onípàsípààrọ̀ owó dànù, àti tábìlì àwọn tí ó ń ta ẹyẹlẹ́ Ó wí fún wọn pé, A sáà ti kọ ọ́ pé, Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi, ṣùgbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà A sì mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní tẹ̀ḿpìlì, ó sì mú wọ́n láradá Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin rí àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá wọ̀nyí, ti wọ́n sì tún ń gbọ́ tí àwọn ọmọdé ń kigbé nínú tẹ́ḿpìlì pé, Hòsánà fún ọmọ Dáfídì, inú bí wọn Wọ́n sì bí i pé, Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ Jésù sí dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni, Àbí ẹ̀yin kò kà á pé Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ-ọmú, ni a ó ti máa yìn mí Ó sì fi wọ́n sílẹ̀, ó lọ sí Bẹ́tánì Níbẹ̀ ni ó dúró ní òru náà Ní òwúrọ̀ bí ó ṣe ń padà sí ìlú, ebi ń pa á Ó sì ṣàkíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lẹ́bàá ojú ọ̀nà, ó sì lọ wò ó bóyá àwọn èso wà lórí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ kan, ewé nìkan ni ó wà lórí rẹ̀ Nígbà náà ni ó sì wí fún igi náà pé, Kí èso má tún so lórí rẹ mọ́ Lójú kan náà igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì gbẹ Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí èyí, ẹnú yà wọn, wọ́n béèrè pé, Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ kíákíà Jésù wí fún wọn pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin bá lè ní ìgbàgbọ́ láì síyè méjì, nígbà náà ẹ̀yin yóò lè ṣe irú tí a se sí igi ọ̀pọ̀tọ́, Ẹ̀yin yóò lè sọ fún òkè yìí pé, Yí ipò padà sínú òkun, yóò sì ríbẹ́ẹ̀ Bí ẹ̀yin bá gbàgbọ́, ẹ̀yin lè rí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè nínú àdúrà gbà Jésù wọ tẹ̀ḿpìlì, nígbà tí ó ń kọ́ni, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù tọ̀ ọ́ wá Wọ́n béèrè pé nípa àṣẹ wo ni o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí Ta ni ó sì fún ọ ni àsẹ yìí Jésù sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, Èmi yóò si bí yin léère ohun kan pàtọ́, bí ẹ̀yin bá lé sọ fún mi, nígbà náà èmi yóò sọ fún yín, àṣẹ tí Èmi fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí Níbo ni ìtẹ̀bọmi Jóhànù ti wa Láti ọ̀run wá ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, Bí àwa bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun yóò wí fún wa pé, È é ha ti ṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́ Ní ìdà kejì, bí àwa bá sì sọ pé, Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, àwa bẹ̀rù ìjọ ènìyàn, nítorí gbogbo wọ́n ka Johanu sí wòlíì Nítorí náà wọ́n sì dáhùn pé, Àwa kò mọ̀ Nígbà náà ni ó wí pé, Nítorí èyí, èmi kò ní sọ àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín Kí ni ẹ rò nípa eléyìí Ọkùnrin kan ti ó ní àwọn ọmọkùnrin méjì Ó sọ fún èyí ẹ̀gbọ́n pé, Ọmọ, lọ ṣíṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí Ó sì dá baba rẹ̀ lóhùn pé, Èmi kò ní í lọ, ṣùgbọ́n níkẹyìn ó yí ọkàn padà, ó sì lọ Nígbà náà ni baba yìí tún sọ fún èyi àbúrò pé, Lọ ṣiṣẹ́ ní oko Ọmọ náà sì sọ pé, Èmi yóò lọ, baba, ṣùgbọ́n kò lọ rárá Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, Èyí ẹ̀gbọ́n ni Jésù wí fún wọn pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó-òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run ṣíwájú yín Nítorí Jòhánù tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó-òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́ Ẹ gbọ́ òwe mìíràn Baálé ilé kan tí ó gbin àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ifúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé-ìsọ́ Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò Nígbà ti àkókò ìkórè súnmọ́, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn àgbẹ̀ náà láti gba èyí ti ó jẹ tirẹ̀ wá Ṣùgbọ́n àwọn olágbàtọ́jú sì mú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn lu ẹnì kínní, wọn pa èkèjì, wọ́n si sọ ẹ̀kẹ́ta ní òkúta Lẹ́ẹ̀kejì, ó rán àwọn ìránṣẹ́ tí ó pọ̀ ju ti ìṣaájú sí wọn Wọ́n sì tún ṣe bí ti àkọ́kọ́ sí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú Níkẹyìn, baálé ilé yìí rán ọmọ rẹ̀ pàápàá sí wọn Ó wí pé, Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ mi Ṣùgbọ́n bí àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí ti rí ọmọ náà lókèèrè, wọ́n wí fún ara wọn pé, Èyí ni àrólé náà Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì jogún rẹ̀ Wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú ọgbà, wọ́n sì pa á Nítorí náà kí ni ẹ ní èrò wí pé olóko náa yóò ṣe pẹ̀lú àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí nígbà tí ó bá padà dé Wọ́n wí pé, Òun yóò pa àwọn ènìyàn búburú náà run, ní ipò òsì, yóò sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú mìíràn tí yóò fún un ní èso tirẹ̀ lásìkò ìkórè Jésù wí fún wọ́n pé, Àbí ẹ̀yin kò kà á nínú ìwé Mímọ́ pé  Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé Iṣẹ́ Olúwa ni èyí, ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn ẹlòmíràn tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá Ẹni tí ó bá ṣubú lu òkúta yìí yóò di fífọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí òun bá ṣubú lù yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí gbọ́ òwe Jésù, wọ́n mọ̀ wí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Wọn wá ọ̀nà láti mú un, ṣùgbọ́n wọn bẹ̀rù ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n gba Jésù gẹ́gẹ́ bí wòlíì Òwe Àṣè ìgbéyàwó Jésù tún fi òwe sọ̀rọ̀ fún wọn wí pé Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan ti ó múra àṣè ìgbéyàwó ńlá fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Ó rán àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti lọ sọ fún àwọn tí a ti pè tẹ́lẹ̀ pé àsìkò ti tó láti wá sí ibi àsè Ṣùgbọ́n gbogbo wọn kọ̀ láti wá Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mìíràn pé, Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti se àsè náà tán A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyáwó Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó ránṣẹ́ lọ pè kò kán á si Wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ, ọ̀kan sí ọ̀nà oko rẹ̀, òmíràn sí ibi òwò rẹ̀ Àwọn ìyókù sì lu àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ta àbùkù fún wọn, wọ́n lù wọ́n pa Ọba yìí bínú gidigidi, ó sì rán àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, ó sì pa àwọn apànìyàn náà run, ó sì jó ìlú wọn Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Àsè ìgbéyàwó ti ṣe tàn, ṣùgbọ́n àwọn tí a pè kò yẹ fún ọlá náà Ẹ lọ sí ìgboro àti òpópónà kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè rí wá àsè ìgbéyàwó náà Nítorí náà, àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ náà sì jáde lọ sí òpópónà Wọ́n sì mú oríṣìíríṣìí ènìyàn tí wọ́n lè rí wá, àwọn tí ò dára àti àwọn tí kò dára, ilé àṣè ìyàwó sì kún fún àlejò Ṣùgbọ́n nígbà tí ọba sì wọlé wá láti wo àwọn àlejò tí a pè, ó sì rí ọkùnrin kan nínú wọn tí kò wọ àṣọ ìgbéyàwó Ọba sì bi í pé, Ọ̀rẹ́, báwo ni ìwọ ṣe wà níhìn-ín yìí láì ní aṣọ ìgbéyàwó Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà kò ní ìdáhùn kankan Nígbà náà ni ọba wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ dì í tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì sọ ọ́ sínú òkùnkùn lóde níbi tí ẹkún àti ìpayínkeke wà Nítorí ọ̀pọ̀ ni a pè ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn Nígbà náà ni àwọn Farisí pé jọ pọ̀ láti ronú ọ̀nà tì wọn yóò gbà fi ọ̀rọ̀ ẹnu mú un Wọ́n sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hérọ́dù lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé, Olùkọ́, àwa mọ̀ pé olótìítọ́ ni ìwọ, ìwọ sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́ Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í wo ojú ẹnikẹ́ni nítorí tí ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn Nísinsìn yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó-orí fún Késárì tàbí kò tọ́ Ṣùgbọ́n Jésù ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, Ẹ̀yin àgàbàgebè, è é se ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò Ẹ fi owo ẹyọ tí a fi ń san owo-orí kan hàn mi Wọn mú dínárì kan wá fún un, ó sì bi wọ́n pé, Àwòrán tabi èyí Àkọlé tà sì ní Wọ́n sì dáhùn pé, Ti Késárì ni Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Késárì fún Késárì, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnú yà wọ́n Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan náà, àwọn Sadusí tí wọ́n sọ pé kò si àjíǹde lẹ́yìn ikú tọ Jésù wá láti bi í ní ìbéèrè pé, Wọ́n wí pé, Olùkọ́, Mósè wí fún wa pé, bí ọkùnrin kan bá kú ní àìlọ́mọ, kí arákùnrin rẹ̀ sú aya rẹ̀ lópó, kí ó sì bí ọmọ fún un Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, láàrin wa níhìn-in yìí, ìdílé kan wà tí ó ní arákùnrin méje Èyí èkínní nínú wọn gbéyàwó, lẹ́yìn náà ó kú láìlọ́mọ Nítorí náà ìyàwó rẹ̀ di ìyàwó arákùnrin kejì Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ arákùnrin èkejì náà sì tún kú láìlọ́mọ A sì fi ìyàwó rẹ̀ fún arákùnrin tí ó tún tẹ̀lé e Bẹ́ẹ̀ sì ni títítí òun fi di ìyàwó ẹnì kéje Níkẹyìn obìnrin náà pàápàá sì kú Nítorí tí ó ti ṣe ìyàwó àwọn arákùnrin méjèèje, ìyàwó ta ni yóò jẹ́ ní àjíǹde òkú Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn pé, Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí Nítorí ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run Nítorí ní àjíǹde kò ní sí ìgbéyàwó, a kò sì ní fi í fún ni ní ìyàwó Gbogbo ènìyàn yóò sì dàbí àwọn ańgẹ́lì ní ọ̀run Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, nípa ti àjíǹde òkú, tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé Ọlọ́run ń bá yín sọ̀rọ̀ nígbà ti ó wí pé Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run òkú, ṣùgbọ́n tí àwọn alààyè Nígbà ti àwọn ènìyàn gbọ́ èyí ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ Nígbà ti wọ́n sì gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusí lẹ́nu mọ́, àwọn Farisí pé ara wọn jọ Ọ̀kan nínú wọn tí ṣe amòfin dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè yìí Ó wí pé, Olùkọ́ èwo ni ó ga jùlọ nínú àwọn òfin Jésù dáhùn pé,  Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ Èkejì tí ó tún dàbí rẹ̀ ní pé, Fẹ́ràn ọmọ ẹni kejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ Lórí àwọn òfin méjèèjì yìí ni gbogbo òfin àti àwọn wòlíì rọ̀ mọ́ Bí àwọn Farisí ti kó ara wọn jọ, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Kí ni ẹ rò nípa Kírísítì Ọmọ ta ni òun ń ṣe Wọ́n dáhùn pé, Ọmọ Dáfídì Ó sì wí fún wọn pé, Kí ni dé tí Dáfídì, tí ẹ̀mí ń darí, pè é ní Olúwa Nítorí ó wí pé,  Olúwa sọ fún Olúwa mi, Jòkòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀ta rẹ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ   Ǹjẹ́ bí Dáfídì bá pè é ni Olúwa, báwo ni òun se lè jẹ́ ọmọ rẹ̀ Kò sí ẹnì kan tí ó lè sọ ọ̀rọ̀ kan ni ìdáhùn, kò tún sí ẹni tí ó tún bí i léèrè ohun kan mọ́ láti ọjọ́ náà mọ́ Ìdí méje fún ìdájọ́ Nígbà náà ni Jésù wí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé Àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisí jòkòó ní ipò Mósè, Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ gbọ́ tiwọn, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fún yín Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ohun tí wọ́n se, nítorí wọn pàápàá kì í ṣe ohun tí wọn kọ́ yín láti ṣe Wọ́n á di ẹrù wúwo tí ó sì ṣòro láti rù, wọ́n a sì gbé e le àwọn ènìyàn léjìká, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan an Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni Wọ́n ń sọ fílákítérì wọn di gbígbòòrò Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i Wọ́n fẹ́ ipò ọlá ní ibi àsè, àti níbi ìjókòó ìyàsọ́tọ̀ ni sínágọ́gù Wọ́n fẹ́ kí ènìyàn máa kí wọn ní ọjà, kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní Ráábì Ṣùgbọ́n kí a má ṣe pè yín ni Ráábì, nítorí pé ẹnì kan ni Olùkọ́ yín, àní Kírísítì, ará sì ni gbogbo yín Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ni ayé yìí, nítorí baba kan náà ni ẹ ní tí ó ń bẹ ní ọ̀run Kí a má sì ṣe pè yín ní Olùkọ́ nítorí Olùkọ́ kan ṣoṣo ni ẹ̀yin ní, òun náà ni Kírísítì Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá pọ̀ jù nínú yín, ni yóò jẹ́ ìránṣẹ́ yín Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara wọn sílẹ̀ ni a ó gbé ga Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisí, ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin sé ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn ènìyàn nítorí ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ẹ́ wọlé ó wọlé Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisí, ẹ̀yin àgàbàgebè! nítorí ẹ̀yin jẹ ilé àwọn opó run, àti nítorí àṣehàn, ẹ̀ ń gbàdúrà gígùn, nítorí náà ni ẹ̀yin yóò ṣe jẹ̀bí púpọ̀ Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisí, ẹ̀yin àgàbàgebè! nítorí ẹ̀yin rin yí ilẹ̀ àti òkun ká láti yí ẹnì kan lọ́kàn padà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń sọ ọ́ di ọmọ ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po méjì ju ẹ̀yin pàápàá Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin afójú ti ń fi ọ̀nà han afọ́jú! Tí ó wí pé, Ẹnikẹ́ni tí ó ba fi tẹ́ḿpílì búra kò sí nǹkan kan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà inú tẹ́ḿpílì búra, ó di ajigbèsè Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú èwo ni ó ga jù, wúrà tàbí tẹ́ḿpílì tí ó ń sọ wúrà di mímọ́ Àti pé, Ẹmikẹ́ni tó bá fi pẹpẹ búra, kò já mọ́ nǹkan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni tí ó ba fi ẹ̀bùn tí ó wà lórí rẹ̀ búra, ó di ajigbèsè Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú wọ̀nyí! Èwo ni ó pọ̀ jù ẹ̀bùn tí ó wà lórí pẹpẹ ni tàbí pẹpẹ fúnra rẹ̀ tí ó sọ ẹ̀bùn náà di mímọ́ Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fi pẹpẹ búra, ó fi í búra àti gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀ Àti pé, ẹni tí ó bá fi tẹ́mńpílì búra, ó fi í búra àti ẹni tí ń gbé inú rẹ̀ Àti pé, ẹni tí ó bá sì fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ẹni tí ó jókòó lóri rẹ̀ búra Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisí, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin ń gba ìdámẹ́wàá míńtì, áníṣè àti kùmínì, ẹ̀yin sì ti fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú òfin sílẹ̀ láìṣe ìdájọ́, àánú àti ìgbàgbọ́ Wọ̀nyí ni ó tọ́ tí ẹ̀yin ìbá ṣe, ẹ̀yin kò bá fi wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ láìṣe Ẹ̀yin afọ́jú tó ń afójú mọ̀nà! Ẹ tu kòkòrò tó bọ́ sì yín lẹ́nu nù, ẹ gbé ràkúnmí mì Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisí àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè Ẹ̀yin ń fọ òde aago àti àwo ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ìrẹ́jẹ àti ẹ̀gbin gbogbo Ìwọ afọ́jú Farisí, tètè kọ́ fọ inú aago àti àwo, gbogbo aago náà yóò sì di mímọ́ Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisí àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè Ẹ dàbí ibojì fúnfun tí ó dára ní wíwò, ṣùgbọ́n tí ó kún fún egungun ènìyàn àti fún ẹ̀gbin àti ìbàjẹ́ Ẹ̀yin gbìyànjú láti fara hàn bí ènìyàn mímọ́, olódodo, lábẹ́ aṣọ mímọ́ yínni ọkàn tí ò kún fún ìbàjẹ́ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀ wà Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisí, ẹ̀yin àgàbàgebè, nítorí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì tíí ṣe ibojì àwọn olódodo ní ọ̀sọ́ Ẹ̀yin sì wí pé, Àwa ìbá wà ní àsìkò àwọn baba wa, àwa kì bá ní ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì Ǹjẹ́ ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí fún ara yín pé, ẹ̀yin ni ọmọ àwọn tí ó pa àwọn wòlíì Àti pé, ẹ̀yin ń tẹ̀lé ìṣísẹ̀ àwọn baba yín Ẹ̀yin ń kún òsùwọ̀n ìwà búburú wọn dé òkè Ẹ̀yin ejò! Ẹ̀yin paramọ́lẹ̀! Ẹ̀yin yóò ti ṣe yọ nínú ẹbí ọ̀run àpáàdì Nítorí náà èmi yóò rán àwọn wòlíì àti àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí ó kún fún ẹ̀mí mímọ́, àti àwọn akọ̀wé sí yín Ẹ̀yin yóò pa àwọn kan nínú wọn nípa kíkàn wọ́n mọ́ àgbélébùú Ẹ̀yin yóò fi pàṣán na àwọn ẹlòmíràn nínú sínágọ́gù yín, tí ẹ̀yin yóò sì ṣe inúnibíni sí wọn láti ìlú dé ìlú Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ pa, láti ẹ̀jẹ̀ Ábélì títí dé ẹ̀jẹ̀ Ṣákaráyà ọmọ Berekáyà ẹni tí ẹ pa nínú Tẹ́ḿpìlì láàrin ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò wà sórí ìran yìí Jerúsálémù, Jerúsálémù, ìlú tí ó pa àwọn wòlíì, tí ó sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí i Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi tí ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbébọ̀ adíyẹ̀ ti í dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ̀ Wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro Nítorí èmi sọ èyí fún yín, ẹ̀yin kì yóò rí mi mọ́, títí ẹ̀yin yóò fi sọ pé Olùbùkún ni ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa   Àwọn Àmì Òpin Ayé Bí Jésù ti ń kúrò ni tẹ́ḿpílì, àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n fẹ́ fi ẹwà tẹ́ḿpílì náà hàn án Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, Ẹ̀yin kò ha rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí Lóòótọ́ ni mo wí fún yín gbogbo ilé yìí ni a óò wó lulẹ̀, kò ní sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí òmíràn, tí a kì yóò wó lulẹ̀ Bí ó ti jókòó ní orí òkè Ólífì, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ̀ ọ́ wá ní kọ̀kọ̀, wọ́n wí pé, Sọ fún wa nígbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀ Kí ni yóò jẹ́ àmì ìpadàwá rẹ, àti ti òpin ayé Jésù dá wọn lóhùn pé, Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ Nítorí ọ̀pọ̀ yóò wá ní orúkọ mi tí wọn yóò máa pe ara wọn ní Kírísítì náà Wọn yóò ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà Ẹ ó máa gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má se jáyà nítorí nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣe kí ó ma ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe àkókò náà Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba Ìyàn àti ilẹ̀ mímì yóò wà ní ibi púpọ̀ Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ó ń bọ̀ Nígbà náà ni a ó sì dá a yín lóró A ó pa yín, a ó sì kórìíra yín ni gbogbo ayé, nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ tèmi Àti pé, ọ̀pọ̀ nínú yín yóò kọsẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣòfófó ara yín, ẹ̀yin yóò kórìíra ara yín pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì èké yóò farahàn, wọn yóò tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jẹ Ẹ̀ṣẹ̀ yóò wà níbi gbogbo, yóò sì sọ ìfẹ́ ọ̀pọ̀ di tútù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbà là A ó sì wàásù ìyìn rere nípa ìjọba náà yí gbogbo ayé ká, kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lè gbọ́ ọ, nígbà náà ni òpin yóò dé ní ìkẹyìn Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìṣọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Dáníẹ́lì sọ, tí ó bá dúró ní ibi mímọ́, Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn tí ó wà ní Jùdíà sá lọ sí àwọn orí òkè Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀ kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀ Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ lọ́mú ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì! Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì sẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsìn yìí irú rẹ̀ kì yóò sì sí Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, Wo Kírísítì náà, tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́ Nítorí àwọn èké Kírísítì àti àwọn èké wòlíì yóò dìde Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ Wò ó, mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀ Nítorí náà, bí ẹnìkan bá sọ fún yín pé, Olùgbàlà ti dé, àti pé, Ó wà ní ihà, ẹ má ṣe wàhálà láti lọ wò ó, tàbí tí wọ́n bá ní ó ń fara pamọ́ sí iyàrá, ẹ má ṣe gbà wọn gbọ́ Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-òòrùn títí dé ìwọ̀-oòrun, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ-Ènìyàn yóò jẹ́ Nítorí ibikíbi tí òkú bá gbé wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ igún ń kójọ pọ̀ sí Lójú kan náà lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,  ni oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀, agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì Nígbà náà ni àmì Ọmọ-Ènìyàn yóò si fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ-Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá Yóò sì rán àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú ohùn ìpè ńlá, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti ọ̀run jọ Nísinsìn yìí, ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́ Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti ń yọ titun tí ó bá sì ń ru ewé, ẹ̀yin mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́ tòòsí, Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí i tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìpadabọ̀ mi dé tán lẹ́yìn ìlẹ̀kùn Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò kọjá títí tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ Ọ̀run àti ayé yóò ré kọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò ré kọjá Ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kan ti ó mọ ọjọ́ àti wákàtí tí òpin náà yóò dé, àwọn ańgẹ́lì pàápàá kò mọ̀ ọ́n Àní, ọmọ Ọlọ́run kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba mi nìkan ṣoṣo ló mọ̀ ọ́n Bí ó ṣe rí ní ìgbà ayé Nóà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ-Ènìyàn yóò sì rí Nítorí bí àwọn ọjọ́ náà ti wà ṣáájú ìkún omi, tí wọ́n ń jẹ́ tí wọ́n ń mu, tí wọ́n ń gbéyàwó, tí wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí tí ó fi di ọjọ́ tí Nóà fi bọ́ sínú ọkọ̀ Ènìyàn kò gbàgbọ́ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ títí tí ìkún omi fi dé nítòótọ́, tí ó sì kó wọn lọ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ-Ènìyàn Àwọn ọkùnrin méjì yóò máa ṣiṣẹ́ nínú oko, a yóò mú ẹnì kan, a ó sì fi ẹnì kejì sílẹ̀ Àwọn obìnrin méjì yóò jùmọ̀ máa lọ ọlọ́ pọ̀, a yóò mú ọ̀kan, a ó fi ẹnì kejì sílẹ̀ Nítorí náà, ẹ múra sílẹ̀, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín yóò dé Ṣùgbọ́n, kí ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí náà tí olè yóò wá, ìbá máa ṣọ́nà, òun kì bá ti jẹ́ kí a já wọ ilé rẹ̀ Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ wà ní ìmúra-sílẹ̀, nítorí ní wákàtí àìròtẹ́lẹ̀ ni dídé Ọmọ-Eènìyàn yóò jẹ́ Ǹjẹ́ olóòótọ́ àti ọlọ́gbọ́n ọmọ-ọ̀dọ̀ wo ni olúwa rẹ̀ lè fi ṣe olùbojútó ilé rẹ̀ láti bọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́ Alábùkún fún ni ọmọ-ọ̀dọ̀ ti olúwa rẹ̀ dé tí ó sì bá a lórí iṣẹ́ ṣíṣe Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi yóò sì fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe alákòóso gbogbo ohun tí mo ní Ṣùgbọ́n bí ọmọ-ọ̀dọ náà bá jẹ́ ènìyàn búburú, tí ó sì ń wí fún ara rẹ̀ pé, olúwa mi kì yóò tètè dé Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ si í fi ìyà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó sì ń mu àmupara Nígbà náà ni olúwa ọmọ-ọ̀dọ̀ yóò wá ní ọjọ́ àti wákàtí tí kò rétí Yóò sì jẹ ẹ́ ní ìyà gidigidi, yóò sì rán an sí ìdájọ́ àwọn àgàbàgebè, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà Òwe Àwọn Wúndíá Mẹ́wàá Nígbà náà ni ó fi ìjọba ọ̀run wé àwọn wúńdíá mẹ́wàá Ti wọ́n gbé àtùpa wọn láti lọ pàdé ọkọ ìyàwó Márùn-ún nínú wọn jẹ́ ọlọgbọ́n, márùn-ún nínú wọn ni wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n gbé àtùpà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mú epo kankan lọ́wọ́ Àwọn ọlọ́gbọ́n mú epo sínú kólòbó dání pẹ̀lú àtùpà wọn Nígbà tí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé wọn sì sùn Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, igbe ta sókè, Wò ó, ọkọ ìyàwó ń bọ̀, ẹ jáde sóde láti pàdé rẹ̀ Nígbà náà ni àwọn wúńdíá sì tají, wọ́n tún àtùpà wọn ṣe Àwọn aláìgbọ́n márùn-ún tí kò ní epo rárá bẹ àwọn ọlọgbọ́n pé kí wọn fún àwọn nínú èyí tí wọ́n ní nítorí àtùpà wọn ń kú lọ Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n márùn-ún dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó má baà ṣe aláìtó fún àwa àti ẹ̀yin, ẹ kúkú tọ àwọn tí ń tà á lọ, kí ẹ sì rà fún ara yín Ní àsìkò tí wọ́n lọ ra epo tiwọn, ni ọkọ ìyàwó dé Àwọn wúńdíá tí ó múra tán bá a wọlé sí ibi àṣè ìgbéyàwó, lẹ̀yìn náà, a sì ti ìlẹ̀kùn Ní ìkẹyìn ni àwọn wúńdíá márùn-ún ìyókù dé, wọ́n ń wí pé, olúwa, olúwa, sílẹ̀kùn fún wa Ṣùgbọ́n ọkọ ìyàwó dáhùn pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún yín èmi kò mọ̀ yín rí Nítorí náà, Ẹ máa ṣọ́nà Nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí Ọmọ-Ènìyàn yóò dé A sì tún fi ìjọba ọ̀run wé ọkùnrin kan tí ó ń lọ sí ìrìn-àjò Ó pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì kó ohun ìní rẹ̀ fún wọn Ó fún ọ̀kan ni tálẹ́ǹtì márùn-ún, ó fún èkejì ni tálẹ́ntì méjì, ó sì fún ẹ̀kẹta ni tálẹ́ntì kan, ó fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti mọ, ó sì lọ ìrìn-àjò tirẹ̀ Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti fi owó náà ṣòwò Láìpẹ́, ó sì jèrè márùn-ún mìíràn Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì náà fi tirẹ̀ ṣòwò Láìpẹ́, ó sì jèrè talẹ́ntì méjì mìíràn Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ò gba tálẹ́ǹtì kan, ó wa ihò ní ilẹ̀, ó sì bo owó ọ̀gá mọ́ ibẹ̀ Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, olúwa àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ dé láti àjò rẹ̀ Ó pè wọ́n jọ láti bá wọn sírò owó rẹ̀ Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún, mú márùn-ún mìíràn padà wá, ó wí pé, olúwa, ìwọ ti fi tálẹ́ǹtì márùn-ún fún mi, mo sì ti jèrè márùn-ún mìíràn pẹ̀lú rẹ̀ Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, O ṣeun ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere àti olóòótọ́ ìwọ ṣe olóòótọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ Èyí tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì wí pé Olúwa, ìwọ fún mi ní tálẹ́ǹtì méjì láti lò, èmi sì ti jèrè tálẹ́ńtì méjì mìíràn Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé O ṣeun, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere àti olóòótọ́ Ìwọ ti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ ṣe olórí ohun púpọ̀ Ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ Níkẹyìn, ọkùnrin tí a fún ní tálẹ́ǹtì kan wá, ó wí pé, Olúwa, mo mọ̀ pé oǹrorò enìyàn ni ìwọ ń ṣe ìwọ ń kórè níbi tí ìwọ kò gbìn sí, ìwọ ń kó jọ níbi tí ìwọ kò ó ká sí Èmi bẹ̀rù, mo sì lọ pa tálẹ́ńtì rẹ mọ́ sínú ilẹ̀ Wò ó, nǹkan rẹ nìyìí Ṣùgbọ́n olúwa rẹ̀ dáhùn pé, Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé èmi ń kórè níbi tí èmi kò fúnrúgbìn sì, èmi sì ń kó jọ níbi tí èmi kò ó ká sí Nígbà náà ìwọ ìbá kúkú fi owó mi sí ilé ìfowópamọ́ tí èmi bá dé èmi ìbá le gba owó mi pẹ̀lú èrè  Ó sì páṣẹ kí a gba tálẹ́ǹtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí a sì fún ọkùnrin tí ó ní tálẹ́ǹtì mẹ́wàá Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní a ó fún sí i, yóò sí tún ní sí lọ́pọ̀lọpọ̀ Ṣùgbọ́n láti ọwọ́ ẹni tí kò ní ni a ó ti gbà èyí tí ó ní Nítorí ìdi èyí, gbé aláìlérè ọmọ-ọ̀dọ̀, jù ú sínú òkùnkùn lóde, ibẹ̀ niẹ̀kún òun ìpayínkeke yóò gbé wà Ṣùgbọ́n nígbà ti Ọmọ-Ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo ní ọ̀run Gbogbo orílẹ̀-èdè ni a ó kó jọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn ayé sí ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe é ya àgùntàn kúrò lára àwọn ewúrẹ́ Òun yóò sì fi àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún àti ewúrẹ́ sí ọwọ́ òsì Nígbà náà ni Ọba yóò wí fún àwọn tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún pé, Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún fún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè fún yín láti ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé Nítorí ebí pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òrùngbẹ gbẹ mí, ẹyin sì fún mi ní omi Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín Mo wà ní ìhòòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yín bẹ̀ mí wò Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò fèsì pé, Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì fún ọ ní oúnjẹ Tàbí tí òrùngbẹ ń gbẹ ọ́ tí a sì fún ọ ní ohun mímu Tàbí tí o jẹ́ àlejò tí a gbà ó sínú ilé wa Tàbí tí o wà ní ìhòòhò, tí a sì daṣọ bò ọ́ Nígbà wo ni a tilẹ̀ rí i tí o ṣe àìsàn, tàbí tí o wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, tí a bẹ̀ ọ́ wò Ọba náà yóò sì dáhùn yóò sì wí fún wọn pé, lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin ṣe nǹkan wọ̀nyí fún àwọn arákùnrin mi yìí tí o kéré jú lọ, ẹ̀ ń ṣe wọn fún mi ni Nígbà náà ni yóò sọ fún àwọn tí ọwọ́ òsì pé, Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún, sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti tọ́jú fún èṣù àti àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ Nítorí tí ebi pa mi, ẹ̀yin kò tilẹ̀ bọ́ mi, òrùngbẹ́ gbẹ mi, ẹ kò tilẹ̀ fún mi ní omi láti mu Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mi sílé Mo wà ní ìhòòhò, ẹ̀yin kò fi aṣọ bò mi Mo ṣàìsàn, mo sì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ẹ̀yin kò bẹ̀ mí wò Nígbà náà wọn yóò dáhùn pé, Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ, tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òrùngbẹ ń gbẹ ọ́, tàbí tí o ṣàìsàn, tàbí tí o wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, tí a kò sí ràn ọ́ lọ́wọ́ Yóò sì dáhùn pé, Nígbà tí ẹ̀yin ti kọ̀ láti ran ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ́wọ́ nínú arákùnrin mi ẹ̀yin tí kọ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi ni Nígbà náà wọn yóò sì kọjá lọ sínú ìyà àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun Ìdìtẹ̀ Mọ́ Jésù Nígbà tí Jésù ti parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀, ó wí fún wọn pé, Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀ Àti pé, a ó fi Ọmọ-Ènìyàn lé ni lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú Ní àsìkò tí Jésù ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfàá àti àwọn àgbààgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfàá náà tí à ń pè ní Káíáfà Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jésù pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀ Nígbà tí Jésù wà ní Bẹ́tánì ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Símónì adẹ́tẹ̀ Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìgò òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yin rí i, inú bí wọn Wọ́n wí pé, Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí È é ha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní Jésù ti mọ èrò ọkàn wọn, ó wí pé, È é ṣe ti ẹ̀yin fi ń dá obìnrin yìí lẹ́bi Ó ṣe ohun tí ó dára fún mi Ẹ̀yin yóò ní àwọn aláìní láàrin yín nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n, ẹ̀yin kò le rí mi nígbà gbogbo Nípa dída òróró ìkunra yìí sí mi lára, òun ń ṣe èyí fún ìsìnkú mi ni Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, a ó sì máa ṣe ìrántí rẹ̀ nígbà gbogbo fún ìṣesí rẹ̀ yìí Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìyìn rere yìí ní gbogbo àgbáyé ni a ó ti sọ ìtàn ohun tí obìnrin yìí ṣe Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn àpósítélì méjìlá ti à ń pè ní Júdásì Ìskáríọ́tù lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà Òun sì béèrè pé, Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jésù lé yín lọ́wọ́ Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà Ó sì gbà á Láti ìgbà náà lọ ni Júdásì ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́ Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ àkàrà àìwú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ Jésù wá pé, Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a pèsè sílẹ̀ láti jẹ àsè ìrékọjá Jésù sì dáhùn pé, Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, Olùkọ́ wa wí pé Àkókò mi ti dé Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ   Nítorí náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ fún wọn Wọ́n sì tọ́jú oúnjẹ àsè ti ìrékọjá níbẹ̀ Ní àṣálẹ́ ọjọ́ kan náà, bí Jésù ti jókòó pẹ̀lú àwọn méjìlá, nígbà tí wọ́n sì ń jẹun, ó wí pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀kan nínú yín yóò fi mí hàn Ìbànújẹ́ sì bo ọkàn wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i bi í pé, Olúwa, èmi ni bí Jésù dáhùn pé, Ẹni ti ó bá mi tọwọ́ bọ inú àwo, ni yóò fi mi hàn Ọmọ-Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀ ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà lọ́wọ́ ẹni tí a ó ti fi Ọmọ ènìyàn hàn! Ìbá kúkú sàn fún ẹni náà, bí a kò bá bí Júdásì, ẹni tí ó fi í hàn pẹ̀lú béèrè pé, Ráábì, èmi ni bí Jésù sì dá a lóhùn pé, Ìwọ wí i Bí wọ́n ti ń jẹun, Jésù sì mú ìwọ̀n àkàrà kékeré kan, lẹ́yìn tí ó ti gbàdúrà sí i, ó bù ú, Ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó wí pé, Gbà, jẹ nítorí èyí ni ara mi Bákan náà, ó sì mú aago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sí fún wọn Ó wí pé, Kí gbogbo yín mu nínú rẹ̀ Nítorí èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi, tí ó ń ṣe májẹ̀mú titun, tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn Sì kíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ mi Èmi kì yóò tún mu nínú ọtí wáìnì yìí mọ́ títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò mu ún ní titun pẹ̀lú yín ní ìjọba Baba mi Wọ́n sì kọ orin kan, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sórí òkè Ólífì Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, Gbogbo yín ni yóò kọsẹ̀ lára mi ní òru òní Nítorí a ti kọ ọ́ pé  Èmi yóò kọlu olùsọ́ àgùntàn a ó sì tú agbo àgùntàn náà ká kiri Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo bá jí dìde, èmi yóò ṣáájú yín lọ sí Gálílì Pétérù sì dá a lóhùn pé, Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ Jésù wí fún un pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ pé, ní òru yìí, kí àkùkọ kí ó tó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta Pétérù wí fún un pé, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ láti kú pẹ̀lú, èmi kò jẹ́ sẹ́ ọ Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí Nígbà náà ni Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibi kan ti à ń pè ní ọgbà Gétísémánì, ó wí fún wọn pé, Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbàdúrà lọ́hùn-ún ni Ó sì mú Pétérù àti àwọn ọmọ Sébédè méjèèjì Jákọ́bù àti Jòhánù pẹ̀lú rẹ̀, ìrora àti ìbànújẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí i gba ọkà rẹ̀ Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, Ọkàn mi gbọgbẹ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́ títí dé ojú ikú, ẹ dúró níhìn-ín yìí, kí ẹ máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi Òun lọ sí iwájú díẹ̀ sí i, ó sì dojú bolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé, Baba mi, bí ó bá ṣeé se, jẹ́ kí a mú aago yìí ré mi lórí kọjá, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tìrẹ ni mo fẹ́ kí ó ṣẹ, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi Bí ó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó bá wọn, wọ́n ń sùn Ó kígbe pé, Pétérù, ẹ̀yin kò tilẹ̀ lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan Ẹ kún fún ìṣọ́ra, kí ẹ sì máa gbàdúrà kí ẹ̀yin má ba à bọ́ sínú ìdẹ́wò Nítorí Ẹ̀mi ń fẹ́ nítòótọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara Ó tún fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kejì, ó sí gbàdúrà pé, Baba mi, bí aago yìí kò bá lè ré mi lórí kọjá àfi tí mo bá mu ún, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe Nígbà tí ó tún padà dé sọ́dọ̀ wọn, Ó rí i pé wọn ń sùn, nítorí ojú wọn kún fún oorun Nítorí náà, ó fi wọn sílẹ̀ ó tún padà lọ láti gbàdúrà nígbà kẹta, ó ń wí ohun kan náà Nígbà náà ni ó tọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó wí pé, Àbí ẹ̀yin sì ń sùn síbẹ̀, ti ẹ sì ń sinmi Wò ó sánmọ̀ wákàtí náà tí dé ti a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a máa lọ! Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mi hàn ń bọ̀ wá! Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Júdásì, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n ti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfàá àti àgbààgbà Júù wá Ẹni tí ó sì fi í hàn ti fi àmì fún wọn, pé, Ẹnikẹ́ni tí mo bá fi ẹnu kò ní ẹnu, òun náà ni ẹ mú un Nísinsìn yìí, Júdásì wá tààrà sọ́dọ̀ Jésù, ó wí pé, Àlàáfíà, Ráábì ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu Jésù wí pé, Ọ̀rẹ́, kí ni nǹkan tí ìwọ bá wá Àwọn ìyókù sì sún ṣíwájú wọ́n sì mú Jésù Sì wò ó, ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà pẹ̀lú Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà yọ, ó sì ṣá ọ̀kan tí i ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé e ní etí sọnù Jésù wí fún un pé, Fi idà rẹ bọ àkọ̀ nítorí àwọn tí ó ń fi idà pa ni Ìwọ kò mọ̀ pé èmi lè béèrè lọ́wọ́ Baba mi kí ó fún mi ju légíónì ańgẹ́lì méjìlá Òun yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ lẹsẹ̀kẹsẹ̀ Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe eléyìí ọ̀nà wo ni a ó fi mú ìwé Mímọ́ ṣẹ, èyí tí ó ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nísinsìn yìí Nígbà náà ni Jésù wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, Tàbí èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹ̀ḿpìlì, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà Ṣùgbọ́n gbogbo wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a tì ẹnu àwọn wòlíì sọ, tí a kọ sínú ìwé Mímọ́ lè ṣẹ Nígbà yìí gan-an ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sá lọ Àwọn tí ó mú Jésù fà á lọ sí ilé Káíáfà, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olúkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbààgbà Júù péjọ sí Ṣùgbọ́n Pétérù ń tẹ̀lé e lókèèrè Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jésù Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé-ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù pé jọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jésù, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan Níkẹyìn, àwọn ẹlẹ́rìí méjì dìde Wọn wí pé, Ọkùnrin yìí sọ pé, èmi lágbára láti wó tẹ̀ḿpìlì Ọlọ́run lulẹ̀, èmi yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ mẹ́ta   Nígbà náà ni olórí àlùfáà sì dìde, ó wí fún Jésù pé, Ẹ̀rí yìí ńkọ́ Ìwọ sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ìwọ kò sọ bẹ́ẹ̀ Ṣùgbọ́n Jésù dákẹ́ rọ́rọ́ Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè Kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kírísítì Ọmọ Ọlọ́run Jésù sì dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí, Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ-Ènìyàn ti yóò jókóó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùukù Nígbà náà ni olórí àlùfáà fa aṣọ òun tikáraa rẹ̀ ya Ó sì kígbe pé, Ọ̀rọ̀ òdì! Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún Gbogbo yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì rẹ̀ Kí ni ìdájọ́ yín Ki ni ẹ ti rò èyí sí Gbogbo wọn sì kígbe lọ́hùn kan pé, Ó jẹ̀bi ikú! Wọ́n tu itọ́ sí i ní ojú Wọ́n gbá a lẹ́sẹ̀ẹ́ Àwọn ẹlòmíràn sì gbá a lójú Wọ́n wí pé, Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wa! Ìwọ Kírísítì, Ta ni ẹni tí ó ń lù Ọ́ Lákòókò yìí, bí Pétérù ti ń jókòó ní ọgbà ìgbẹ́jọ́, ọmọbìnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, Ìwọ wà pẹ̀lú Jésù ti Gálílì Ṣùgbọ́n Pétérù ṣẹ̀ ní ojú gbogbo wọn pé Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí ẹ ń sọ nípa rẹ̀ Lẹ́yìn èyí, ní ìta lẹ́nu ọ̀nà, ọmọbìnrin mìíràn tún rí i, ó sì wí fún àwọn tí ó dúró yíká pé, Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jésù ti Násárẹ́tì Pétérù sì tún ṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú ìbúra pé, Èmi kò tilẹ̀ mọ ọkùnrin náà rárá Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó ń dúró níbi ìran yìí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí pé, Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àwa mọ̀ ọ́ Èyí sì dá wa lójú nípa àmì ohùn rẹ̀ tí ó ń ti ẹnu rẹ jáde Pétérù sì tún bẹ̀rẹ̀ sí íbúra ó sì fi ara rẹ̀ ré wí pé, Mo ní èmi kò mọ ọkùnrin yìí rárá Lójú kan náà àkùkọ sì kọ Nígbà náà ni Pétérù rántí nǹkan tí Jésù ti sọ pé, Kí àkùkọ tóó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta Òun sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò Júdásì lọ Pokùnṣo Ní òwúrọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù tún padà láti gbìmọ bí wọn yóò ti ṣe pa Jésù Lẹ́yìn èyí, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè é, wọ́n sì jọ̀wọ́ rẹ̀ fún Pílátù tí i ṣe gómìnà Nígbà tí Júdásì, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù Ó wí pé, Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni! Nígbà náà ni Júdásì da owó náà sílẹ̀ nínú tẹ̀ḿpìlì Ó jáde, ó sì lọ pokùnṣo Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà Wọ́n wí pé, Àwa kò lè fi owó yìí pẹ̀lú owó ìkójọpọ̀ Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni Nítorí náà wọ́n pínnú, láti fi owó náà ra ilẹ̀ kan, níbi tí àwọn amọ̀kòkò ti ń rí amọ̀ wọn, àti láti lo ilẹ̀ náà fún ìsìnkú fún àwọn àlejò tí ó bá kú ní Jerúsálémù Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní Ìlẹ̀ Ẹ̀jẹ̀ títí di òní Èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremáyà wí pé, Wọ́n sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí àwọn ènìyàn Ísírẹ̀lì díye lé e Wọ́n sì fi ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn amọ̀kòkò gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ Nígbà náà ni Jésù dúró níwájú Baálẹ̀ láti gba ìdájọ́ Baálẹ̀ sì béèrè pé, Ṣe ìwọ ni Ọba àwọn Júù Jésù dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí tí ìwọ wí i Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfàà àti àwọn àgbààgbà Júù fi gbogbo ẹ̀sùn wọn kàn án, Jésù kò dáhùn kan Nígbà náà ni Pílátù, béèrè lọ́wọ́ Jésù pé, Àbí ìwọ kò gbọ́ ẹ̀rí tí wọn ń wí nípa rẹ ni Jésù kò sì tún dáhùn kan Èyí sì ya Baálẹ̀ lẹ́nu Ó jẹ́ àṣà Baálẹ̀ láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni Ní àsìkò náà ọ̀daràn paraku kan wà nínú ẹ̀wọ̀n tí à ń pè Bárábbà Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti pé jọ ṣíwájú ilé Pílátù lówúrọ̀ ọjọ́ náà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Ta ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín, Bárábbà tàbí Jésù, ẹni tí ń jẹ́ Kírísítì Òun ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọn fi fà á lé òun lọ́wọ́, Bí Pílátù sì ti ṣe jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé, Má ṣe ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú ọkùnrin aláìṣẹ̀ náà Nítorí mo jìyà ohun púpọ̀ lójú àlá mi lónìí nítorí rẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù rọ àwọn ènìyàn, láti béèrè kí a dá Bárábà sílẹ̀, kí a sì béèrè ikú fún Jésù Nígbà tí baálẹ́ sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Èwo nínú àwọn méjèèjì yìí ni ẹ̀ ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín Àwọn ènìyàn sì kígbe padà pé, Bárábbà! Pílátù béèrè pé, Kí ni kí èmi ṣe sí Jésù ẹni ti a ń pè ní Kírísítì Gbogbo wọn sì tún kígbe pé, Kàn án mọ́ àgbélébùú! Pílátù sì béèrè pé, Nítorí kí ni Kí ló ṣe tí ó burú Wọ́n kígbe sókè pé, Kàn án mọ́ àgbélébùú! Kàn án mọ́ àgbélébùú! Nígbà tí Pílátù sì rí i pé òun kò tún rí nǹkan kan ṣe mọ́, àti wí pé rògbòdìyàn ti ń bẹ̀rẹ̀, ó béèrè omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó wí pé, Ọrùn mí mọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí Ẹ̀yin fúnraa yín, ẹ bojú tó o! Gbogbo àgbájọ náà sì ké pé, Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí wa, àti ní orí àwọn ọmọ wa! Nígbà náà ni Pílátù dá Bárábà sílẹ̀ fún wọn Lẹ́yìn tí òun ti na Jésù tán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti mú un lọ kàn mọ́ àgbélébùú Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun baálẹ̀ mú Jésù lọ sí gbọ̀ngàn ìdájọ́ wọ́n sì kó gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tì í Wọ́n tú Jésù sì ìhòòhò, wọ́n sì wọ̀ ọ́ láṣọ òdòdó, Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún Wọ́n sì fi dé e lórí Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, Kábíyèsí, Ọba àwọn Júù! Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án mọ́ ọn lórí Nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín tán, wọ́n bọ́ aṣọ ara rẹ̀ Wọ́n tún fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́ Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́ àgbélébùú Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kíréné tí à ń pè ní Símónì Wọ́n sì mú ọkùnn náà ní túlààsì láti ru àgbélébùú Jésù Wọ́n sì jáde lọ sí àdúgbò kan tí à ń pè ní Gọ́lígọ́tà, Níbẹ̀ ni wọn ti fún un ni ọtí wáìnì tí ó ní egbòogi nínú láti mu Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti kàn án mọ́ àgbélébùú, wọ́n dìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀ Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé ÈYÍ NI JÉSÙ, ỌBA ÀWỌN JÚÙ síbẹ̀ Wọ́n kan àwọn olè méjì pẹ̀lú rẹ̀ ní òwúrọ̀ náà Ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ̀ Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń bú u Wọ́n sì ń mi orí wọn pé Ìwọ tí yóò wó tẹ́ḿpìlì, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ-Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀ kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là! Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbààgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà Wọ́n kẹ́gàn Rẹ̀ pé, Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀ Ìwọ ọba àwọn Ísírẹ̀lì Sọ̀ kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsìn yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́ Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run Bákan náà, àwọn olè tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Rẹ̀ fi í ṣe ẹlẹ́yà Láti wákàtí kẹfà ni òkùnkùn fi sú bo gbogbo ilẹ̀ títí dé wákàtí kẹsàn-án ọjọ́ Níwọ̀n wákàtí kẹsàn-án ní Jésù sì kígbe ní ohùn rara wí pé, Èlí, Èlí, Làmá Sàbákitànì Ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, è é ṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò yé díẹ̀ nínú àwọn ẹni tí ń wòran, nígbà tíwọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wọ́n wí pé ọkùnrin yìí ń pe Èlíjà Lẹ́sẹ̀ kan náà, ọ̀kan nínú wọn sáré, ó mú kànrìkàn, ó tẹ̀ ẹ́ bọ inú ọtí kíkan Ó fi lé orí ọ̀pá, ó gbé e sókè láti fi fún un mu Ṣùgbọ́n àwọn ìyókù wí pé, Ẹ fi í sílẹ̀ Ẹ jẹ́ kí a wò ó bóyá Èlíjà yóò sọ̀ kalẹ̀ láti gbà á là Nígbà tí Jésù sì kígbe ní ohùn rara lẹ́ẹ̀kan sí i, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀, ó sì kú Lójú kan náà aṣọ ìkélé tẹ̀ḿpìlì fàya, láti òkè dé ìsàlẹ̀ Ilẹ̀ sì mì tìtì Àwọn àpáta sì sán Àwọn isà òkú sì sí sílẹ̀ Ọ̀pọ̀ àwọn olódodo ọkùnrin àti obìnrin tí ó ti kú sì tún jíǹde Wọ́n jáde wá láti isà òkú lẹ́yìn àjíǹde Jésù, wọ́n sì lọ sí ìlú mímọ́ Níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ara han ọ̀pọ̀ ènìyàn Nígbà tí balógun ọ̀run àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ń ṣọ Jésù rí bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọn gidigidi, wọ́n wí pé, Lóòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ní í sẹ! Ọ̀pọ̀ obìnrin tí ó wá láti Gálílì pẹ̀lú Jésù láti tọ́jú Rẹ̀ wọn ń wò ó láti òkèèrè Nínú àwọn obìnrin ti ó wà níbẹ̀ ni Màríà Magidalénì, àti Màríà ìyá Jákọ́bù àti Jósẹ́fù, àti ìyá àwọn ọmọ Sébédè méjèèjì wà níbẹ̀ pẹ̀lú Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatíyà, tí à ń pè ní Jósẹ́fù, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jésù, lọ sọ́dọ̀ Pílátù, ó sì tọrọ òkú Jésù Pílátù sì pàṣẹ kí a gbé é fún un Jósẹ́fù sì gbé òkú náà Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnraa rẹ̀ Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ Màríà Magidalénì àti Màríà kejì wà níbẹ̀, wọn jòkóò dojú kọ ibojì náà Lọjọ́ kejì tí ó tẹlé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí lọ sọ́dọ̀ Pílátù Wọ́n sọ fún un pé, Alàgbà, ẹlẹ́tàn náà wí nígbà kan pé, Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta èmi yóò tún jí dìde Nítorí náà, pàṣẹ kí a ti ibojì rẹ̀ gbọn-ingbọn-in títí ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ má ṣe wá jí i gbé lọ, wọn a sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún gbogbo ènìyàn pé, Òun ti jíǹde, Bí èyí bá ní láti ṣẹlẹ̀, yóò burú fún wa púpọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ Pílátù sì pàṣẹ pé, Ẹ lo àwọn olùṣọ́ yín kí wọn dáàbò bo ibojì náà bí ẹ bá ti fẹ́ Nítorí náà wọ́n lọ Wọ́n sì ṣé òkúta ibojì náà dáadáa Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sí ibẹ̀ láti dáàbò bò ó Àjíndè rẹ̀ Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Máríà Magidalénì àti Màríà kejì lọ sí ibojì Wọ́n rí i pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀ tí ó mú gbogbo ilẹ̀ mì tìtì Nítorí ańgẹ́lì Olúwa ti sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run Ó ti yí òkúta ibojì kúrò Ó sì jókòó lé e lórí Ojú rẹ̀ tàn bí mọ̀nàmọ́ná Aṣọ rẹ̀ sì jẹ́ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́, wọ́n sì wá rìrì wọn sì dàbí òkú Nígbà náà ni ańgẹ́lì náà wí fún àwọn obìnrin náà pé, Ẹ má ṣe bẹ̀rù Mo mọ̀ pé ẹ̀yin ń wá Jésù tí a kàn mọ́ àgbélébùú Ṣùgbọ́n kò sí níhìn-ín Nítorí pé ó ti jíǹde, gẹ́gẹ́ bí òun ti wí Ẹ wọlé wá wo ibi ti wọ́n tẹ́ ẹ sí Nísinsìn yìí, Ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ pé, Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú Àti pé òun ń lọ sí Gálílì síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóògbé rí i, wò ó, o ti sọ fún yin Àwọn obìnrin náà sáré kúrò ní ibojì pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá Wọ́n sáré láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn nípa ìróyìn tí ańgẹ́lì náà fi fún wọn Bí wọ́n ti ń sáré lọ lójijì Jésù pàdé wọn Ó wí pé, Àlàáfíà Wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀ Wọ́n gbá a ní ẹṣẹ̀ mú Wọ́n sì forí balẹ̀ fún un Nígbà náà, Jésù wí fún wọn pé, Ẹ má ṣe bẹ̀rù Ẹ lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi pé, Kí wọ́n lọ tààrà sí Gálílì níbẹ̀ ni wọn yóò gbé rí mi   Bí àwọn obìnrin náà sì ti ń lọ sí ìlú, díẹ̀ nínú àwọn olùṣọ́ tí wọ́n ti ń ṣọ́ ibojì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbààgbà Júù Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́ Wọ́n wí pé, Ẹ sọ fún àwọn ènìyàn pé, Gbogbo yín sùn nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù wá lóru láti jí òkú Rẹ̀ Bí Baálẹ̀ bá sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwa yóò ṣe àlàyé tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn fún un, tí ọ̀rọ̀ náà kì yóò fi lè kó bá yín Àwọn olùṣọ́ sì gba owó náà Wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti darí wọn Ìtàn yìí sì tàn ká kíákíá láàrin àwọn Júù Wọ́n sì gba ìtàn náà gbọ́ títí di òní yìí Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Gálílì ní orí òkè níbi tí Jésù sọ pé wọn yóò ti rí òun Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n forí balẹ̀ fún un Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyè méjì bóyá Jésù ni tàbí òun kọ́ Nígbà náà ni Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi Nítorí náà, Ẹ lọ, ẹ máa kọ́ orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitíísì wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́ Ẹ kọ́ wọn láti máa kíyèsí ohun gbogbo èyí tí mo ti pa láṣẹ fún yín Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín ní ìgbà gbogbo títí tí ó fi dé òpin ayé Jòhánù onítẹ̀bọmi Tún Ọ̀nà náà ṣe Ní ọjọ́ wọ̀n-un-nì, Jòhánù onítẹ̀bọmi wá, ó ń wàásù ní ihà Jùdíà Ó ń wí pé, Ẹ ronú pìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run dé tán Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Àìsáyà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé Ohùn ẹnìkan ti ń kígbe ní ihà, Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ se ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́   Irun ràkúnmí ni a fi hun aṣọ Jòhánù, awọ ni ó sì fi di àmùrè ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀ Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Jerúsálémù àti gbogbo Jùdíà àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà Jọ́dánì Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó ṣe í ìtẹ̀bọmi fún wọn nínú odò Jọ́dánì ibi tí ó ti ń se Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn Farisí àti Sadúsì tí wọ́n ń wá si ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ibínú Ọlọ́run tí ń bọ̀ Ẹ so èso tí ó yẹ fún ìrònú-pìwàdà Kí ẹ má sì ṣe rò nínú ara yin pé, Àwa ní Ábúráhámù ní baba Èmi wí fún yín, Ọlọ́run lè mu àwọn ọmọ jáde láti inú àwọn òkúta wọ̀nyí wá fún Ábúráhámù Nísinsin yìí, a ti fi àáké lè gbòǹgbò igi, àti pé gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a óò gé lulẹ̀ ti a ó sì jù wọn sínú iná Èmi fi omi bamitíìsì yín fún ìrónúpìwàdà Ṣùgbọ́n lẹ́yìn mi ẹnìkan tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, bàtà ẹni tí èmi kò tó gbé Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitíìsì yín Ẹni ti ìmúga ìpakà Rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, yóò gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀, yóò kó ọkà rẹ̀ sínú àká, ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun Nígbà náà ni Jésù ti Gálílì wá sí odò Jọ́dánì kí Jòhánù báà lè ṣe ìtẹ̀bọmi fún un Ṣùgbọ́n Jòhánù kò fẹ́ ṣe ìtẹ̀bọmi fún un, ó wí pé, Ìwọ ni ì bá ṣe ìbamitíìsì fún mi, ṣé ìwọ tọ̀ mí wá fún ìbamitíìsì Jésù sì dáhùn pé, Jọ̀wọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà, ní torí bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ fún wa láti mú gbogbo òdodo ṣẹ Bẹ́ẹ̀ ni Jòhánù gbà, ó sì ṣe ìbamitíìsì fún un Bí a si tí ṣe ìtẹ̀bọmi fún Jésù tán, Ó jáde láti inú omi Ní àkókò náà ọ̀run sí sílẹ̀, Ó sì rí Ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà àti bi mọ̀nàmọ́ná sórí rẹ̀ Ohùn kan láti ọ̀run sì wí pé, Èyí ni ọmọ mi, ẹni ti mo fẹ́ràn, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi Ìdánwò Jésù Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ darí Jésù sí ihà láti dán an wò láti ọwọ́ èsù Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí àwọn òkúta wọ̀nyí di àkàrà Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn pé, A ti kọ ìwé rẹ̀ pé Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá   Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹ̀ḿpìlì Ó wí pé, Bí ìwọ̀ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, Bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ A sa ti kọ̀wé rẹ̀ pé  Yóò pàṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nítorí tìrẹ wọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọn kí ìwọ kí ó má baà fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta   Jésù sì da lóhùn, A sìáà ti kọ ọ́ pé Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò   Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo orílẹ̀-èdè ayé àti gbogbo ẹwà wọn hàn án Ó sì wí fún un pé, Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi Jésù wí fún un pé, Kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, ìwọ Sàtánì! Nítorí a ti kọ ọ́ pé Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ ó sìn   Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn ańgẹ́lì sì tọ̀ ọ́ wá láti jísẹ́ fún un Nígbà tí Jésù gbọ wí pé a ti fi Jòhánù sínu túbú ó padà sí Gálílì Ó kúrò ní Násárẹ́tì, ó sì lọ ígbé Kápánámù, èyí tí ó wà létí òkun Sébúlónì àti Náfítálì Kí èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ pé Iwọ Sébúlónì àti ilẹ̀ Náfítalì ọ̀nà tó lọ sí òkun, ní ọ̀nà Jọ́dánì, Gálílì ti àwọn aláìkọlà, Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùn tí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá, àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì iku ni ìmọ́lẹ̀ tan fún Láti ìgbà náà lọ ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù Ẹ ronú pìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀ Bí Jésù ti ń rìn létí òkun Gálílì, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Símónì, ti à ń pè ní Pétérù, àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀ Wọ́n ń ju sọ àwọn wọn sínú òkun nítorí apẹja ni wọ́n Jésù wi fun wọn pé, Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn Lójú kan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀lé e Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti Jòhánù, arákùnrin rẹ̀ Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú Sébédè baba wọn, wọ́n ń dẹ àwọ̀n wọn, Jésù sì pè wọn náà pẹ̀lú Lójú kan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú-omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Jésù sì rin káàkiri gbogbo Gálílì, ó ń kọ́ni ní sínágọ́gù, ó ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba ọ̀run ó sì ń ṣe ìwòsàn àrùn gbogbo àti àìsàn láàrin gbogbo ènìyàn Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Síríà ká wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú àrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà ó sì wò wọ́n sàn Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Gálílì, Dékápólì, Jerúsálémù, Jùdíà, àti láti òkè odò Jọ́dánì sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Ìwàásù Orí Òkè Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó gun orí òkè lọ ó sì jókòó Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ si tọ̀ ọ́ wá Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn wí pé Alábùkún-fún ni àwọn òtòsì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run Alábùkún-fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a ó tù wọ́n nínú Alábùkún-fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù, nítorí wọn yóò jogún ayé Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa tí òùngbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó Alábùkún-fún ni àwọn aláàánú, nítorí wọn yóò rí àánú gbà Alábùkún-fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́, nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run Alábùkún-fún ni àwọn tonílàjà, nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n Alábùkún-fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí, nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run Alábùkún-fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, ti wọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dà á nù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀ Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fara sin Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òṣùnwọ̀n bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo Ẹ má se rò pé, èmí wá láti pa òfin àwọn wòlíì run, èmi kò wá láti pa wọn rẹ́, bí kò ṣe láti mú wọn ṣẹ Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, àmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé ofin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jù lọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jù lọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sewọn, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run Nítorì náà ni mọ ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisí àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ẹnikẹni tí ó bá pànìyàn yóò wà nínú ewu ìdájọ́ Ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóò wà nínú ewu ìdájọ́ Ẹnikẹ́ni ti ó ba wí fun arakùnrin rẹ̀ pé, Ráákà yóò fara hàn níwájú Sahẹ́ńdìrì ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wí pé Ìwọ wèrè! yóò wà nínú ewu iná ọ̀run àpáàdì Nítorí náà, nígbà tí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá ṣíwájú pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ̀ ni ohùn kan nínú sí ọ Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ Ìwọ kọ́kọ́ lọ ṣe ìlàjà láàrin ìwọ àti arákùnrin rẹ̀ na Lẹ́yìn náà, wá kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ Bá ọ̀tá rẹ làjà kánkán, ẹni tí ó ń gbé ọ lọ sílé ẹjọ́ Ṣe é nígbà ti ó wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò fà ọ́ lé onídajọ lọ́wọ́, onídájọ́ yóò sí fá ọ lé àwọn ẹ̀sọ́ lọ́wọ́, wọ́n a sì sọ ọ́ sínú túbú Lóòótọ ni mo wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀ títítí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó kan tí ó kù Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìrinrin kan ní ìwòkuwò, ti bà a ṣe panṣágà ná ní ọkàn rẹ̀ Bí ojú rẹ ọ̀tún bá mú ọ dẹ́sẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù Ó sàn kí ẹ̀ya ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sínú iná ọ̀run àpáàdì Bí ọwọ́ rẹ ọ̀tún bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀ gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù Ó sàn kí ẹ̀ya ara rẹ kan ṣègbé ju kí gbogbo ara rẹ lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì A ti wí pẹ̀lú pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ gbọdọ̀ fún un ní ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀, àfi nítorí àgbèrè, mú un se àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́ obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ ní ìyàwó ṣe àgbèrè Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàani pé Ìwọ kò gbọdọ̀ búrá èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ sí Olúwa ṣẹ Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, Ẹ má ṣe búra rárá, ìbáà ṣe ìfi-ọ̀run-búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni Tàbí ìfi-ayé-búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni tàbí Jerúsálémù, nítorí olórí ìlú Ọba Ńlá ni Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi Ẹ̀yin tí gbọ́ bí òfin tí wí pé, Ojú fún ojú àti eyín fún eyín Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, Ẹ má ṣe tako ẹni ibi Bí ẹnì kan bá gbá ọ lẹ́rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ òsì sí olúwa rẹ̀ pẹ̀lú Bí ẹnì kan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì Fi fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún ẹni tí ó fẹ́ ya láti lọ́wọ́ rẹ Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, Fẹ́ràn aládúgbo rẹ, kí ìwọ sì kórírà ọ̀ta rẹ̀ Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀ta yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín, Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín bi ń bẹ ní ọ̀run Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan, èrè kí ni ẹ̀yin ní Àwọn agbowó-òde kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ Àti bí ó bá sì jẹ́ pé kìkì àwọn arákùnrin yín nìkan ni ẹ̀yin ń kí, kín ni ẹ̀yin ń ṣe ju àwọn mìíràn Àwọn abọ̀rìṣà kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí Nítorí náà, ẹ jẹ́ pípé, gẹ́gẹ́ bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ṣe jẹ́ pípé Itọrẹ Àánú Ẹ kíyè ṣára kí ẹ má ṣe iṣẹ́ rere yín níwájú àwọn ènìyàn nítorí kí a le rí yín, Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin kò lérè kankan lọ́dọ̀ Baba yín ní ọ̀run Nítorí náà, nígbà ti ẹ ń bá ti fún aláìní, ẹ má ṣe fi kàkàkí kéde rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgàbàgebè ti í ṣe ní sínágọ́gù àti ní ìta gbangba kí àwọn ènìyàn le yìn wọ́n Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè tí wọn ní kíkún Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ńfi fún aláìní, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe, kí ìfúnni rẹ má ṣe jẹ́ mímọ̀ Nígbà náà ni Baba rẹ̀, tí ó sì mọ ohun tí ìkọ̀kọ̀ gbogbo, yóò san án fún ọ Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe ṣe bí àwọn àgàbàgebè, nítorí wọn fẹ́ràn láti máa dúró gbàdúrà ní sínágọ́gù àti ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ènìyàn ti lè rí wọ́n Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní kíkún Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, wọ inú iyàrá rẹ lọ, sé ilẹ̀kùn mọ́ ara rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ ẹni tí ìwọ kò rí Nígbà náà ni Baba rẹ tí ó mọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ, yóò san án fún ọ Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó titorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn Ẹ má ṣe dà bí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà  Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, ọ̀wọ̀ fún orukọ yín, Kí ìjọba yín dé, Ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe ní ayé bí ti ọ̀run Ẹ fún wa ní oúnjẹ oòjọ́ wa lónìí Ẹ dárí gbèsè wa jì wá, Bí àwa ti ń dárí ji àwọn ajigbésè wa, Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdẹwò, Ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín ọ̀run náà yóò dárí jì yín Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́n, baba yín kò níí dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín Nígbà tí ẹ̀yin bá gbààwẹ̀, ẹ má ṣe fa ojú ro bí àwọn àgàbàgebè ṣe máa ń ṣe nítorí wọn máa ń fa ojú ro láti fi hàn àwọn ènìyàn pé àwọn ń gbààwẹ̀ Lóòótọ́ ni mo wí fún yín wọn ti gba èrè wọn ní kíkún Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá gbààwẹ̀, bu òróró sí orí rẹ, kí ó sì tún ojú rẹ ṣe dáradárá Kí ó má ṣe hàn sí ènìyàn pé ìwọ ń gbààwẹ̀, bí kò ṣe sìí Baba rẹ, ẹni tí ìwọ kò rí, àti pé, Baba rẹ tí ó rí ohun tí o ṣe ni ìkọ̀kọ̀, yóò san án fún ọ Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le dípẹtà àti ibi tí àwọn olèlè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti ji í lọ Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara Bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ yóò jẹ́ kìkì ìmọ́lẹ̀ Ṣùgbọ́n bí ojú rẹ kò bá dára, gbogbo ara rẹ ni yóò kún fún òkùnkùn Bí ìmọ́lẹ̀ ti ó wà nínú rẹ bá wáá jẹ́ òkùnkùn, òkùnkùn náà yóò ti pọ̀ tó! Kò sìí ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀ga méjì Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sì Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀ Nítorí náà, mo wí fún yín, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ ó jẹ àti èyí tí ẹ ó mu tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ ó wọ̀ Ṣé ẹ̀mi kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ tàbí ara ni kò ha ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ Ẹ wo àwọn ẹyẹ inú afẹ́fẹ́ wọn kì í gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kó jọ sínú àká, ṣíbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn Ẹ̀yin kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí Ta ni nínú gbogbo yín nípa àníyàn ṣíṣe ti ó lè fi ìṣẹ́jú kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀ Kí ni ìdí ti ẹ fi ń ṣe àníyàn ní ti aṣọ Ẹ wo bí àwọn lílì tí ń bẹ ní igbó ti ń dàgbà Wọn kì í ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú Bẹ́ẹ̀ ni mo wí fún yín pé, a kò ṣe Solómónì lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ bẹ́ẹ̀, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí ti a sì gbà sínú iná lọ́la, kò ha ṣe ni ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́ tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré Nítorí náà, ẹ má ṣe ṣe àníyàn kí ẹ sì máa wí pé, Kí ni àwa yóò jẹ Tàbí Kí ni àwa yóò mu Tàbí Irú aṣọ wo ni àwa yóò wọ̀ Nítorí àwọn kèfèrí ń fi ìwọra wá àwọn nǹkan wọ̀nyí bẹ́ẹ̀ ni Baba yín ní ọ̀run mọ̀ dájúdájú pé ẹ ní ìlò àwọn nǹkan wọ̀nyí Ṣùgbọ́n, ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba rẹ̀ ná àti òdodo rẹ̀, yóò sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín pẹ̀lú Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn ọ̀la, ọ̀la ni yóò ṣe àníyàn ara rẹ̀ Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un Ṣíṣe Ìdájọ́ Ẹnìkejì Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́, kí a má bà dá yín lẹ́jọ́ Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín irú òṣùnwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ̀n, òun ni a ó sì fi wọ̀n fún yín È é tí ṣe tí ìwọ fi ń wo èrúnrún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyè sí ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ, sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tì kara rẹ Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arakùnrin rẹ kúrò Ẹ má ṣe fi ohun mímọ́ fún ajá jẹ, ẹ má sì ṣe sọ ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yín fún ẹlẹ́dẹ̀, bí ẹ̀yin bá se bẹ́ẹ̀ kí wọ́n má bà fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn a sì yí padà sí yín, wọn a sì bù yín jẹ Béèrè, a ó sì fi fún yín wá kiri, ẹ̀yin yóò sì rí kànkùn, a ó sì sí i sílẹ̀ fún yín Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà, ẹni tí ó bá sì wà kiri ń ní, ẹni bá sì kànkùn ni a ó ò si sílẹ̀ fún Ta ni ọkùnrin náà tí ń bẹ nínú yín, bí ọmọ rẹ̀ béèrè àkàrà, tí yóò jẹ́ fi òkúta fún un Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò jẹ́ fún un ní ejò Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí í ṣe ènìyàn búburú bá mọ̀ bí a ti í fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ohun rere fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ Nítorí náà, nínú gbogbo ohunkóhun ti ẹ̀yin bá ń fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ nítorí èyí ni òfin àti àwọn wòlíì Ẹ máa ba ẹnu-ọ̀nà tóótó wọlé gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé Nítorí kékeré ni ẹnu-ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú ọ̀nà náà, ti ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín Ẹ máa sọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n Nípa èso wọn ni a ó fi dá wọn mọ̀ Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára ẹ̀gún ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún èṣùṣú Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, à gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná Nítorí náà, èso wọn ni ẹ̀yin yóò fi dá wọn mọ̀ Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, Olúwa, Olúwa, ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run Ọ̀pọ̀ ni yóò wí fún mi ní ọjọ́ náà pé, Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, àti ní orúkọ rẹ kọ́ ni a fi re ọ̀pọ̀ ẹ̀mú ẹ̀sù jáde, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu Nígbà náà ni èmi yóò wí fún wọn pé, Èmi kò mọ̀ yín rí, ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fi wé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta Òjò sì rọ̀, ikún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà síbẹ̀ síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fi wé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn Òjò sì rọ̀, ìkú n omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó ìwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ Nígbà tí Jésù sì parí sisọ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu ya àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, Nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí i ti olùkọ́ òfin wọn Ọkùnrin Adẹ́tẹ̀ Nígbà tí ó ti orí òkè sọ̀ kalẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Sì wò ó, adẹ́tẹ̀ kan wà, ó wá ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ ó wí pé, Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mi di mímọ́ Jésù si nà ọwọ́ rẹ̀, ó fi bà á, ó wí pé, Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́ Lójú kan náà, ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sì mọ́! Jésù sì wí fún pé, Wò ó, má ṣe sọ fún ẹnì kan Ṣùgbọ́n máa ba ọ̀nà rẹ̀ lọ, fi ara rẹ̀ hàn fún àlúfáà, kí o sì san ẹ̀bùn tí Mósè pa laṣẹ ní ẹ̀rí fún wọn Nígbà tí Jésù sì wọ̀ Kápánámù, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ O sì wí pé, Olúwa, ọmọ-ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ àrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá Jésù sì wí fún un pé, Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá Balógun ọ̀rún náà dahùn, ó wí pé, Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ mi láradá Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi Bí mo wí fún ẹni kan pé, Lọ, a sì lọ, àti fún ẹnì kejì pé, Wá, a sì wá, àti fún ọmọ-ọ̀dọ̀ mi pé, Ṣe èyí, a sì ṣe é Nígbà tí Jésù gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Ísírẹ́lì tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìha ìlà-oòrùn àti ìhà iwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Ábúráhámù àti Ísáákì àti Jákọ́bù jẹun ní ìjọba ọ̀run Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà Nítorí náà Jésù sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀ A sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ náà lára dá ní wákàtí kan náà Nígbà tí Jésù sì dé ilé Pétérù, ìyá ìyàwó Pétérù dùbúlẹ̀ àìsàn ibà Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìrànṣẹ fún wọn Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde A sì mú gbogbo àwọn olókùnrùn láradá Kí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ pé Òun tikara rẹ̀ gbà àìlera wa, ó sì ń ru àrùn wa Nígbà tí Jésù rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó yí i ká, ó pàṣẹ pé kí wọ́n sọdá sí òdìkejì adágún Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ Jésù dá lóhùn pé, Àwọn kọ̀lọ̀lọ̀kọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́ ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú bàbá mi ná Ṣùgbọ́n Jésù wí fún un pé, Má a tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn Nígbà náà ni ó bọ́ sínú ọkọ̀ ojú-omi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì-líle dìde lórí òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀ ṣùgbọ́n Jésù ń sùn Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, Olúwa, gbà wá, àwa yóò rì Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré È é se ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú òkun náà wí gbogbo rẹ̀ sì pa rọ́rọ́ Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, Irú ènìyàn wo ni èyí kódà ìji-líle àti rírú omi òkun gbọ́ tirẹ̀ Nígbà ti ó sì dé àpa kejì ní ilẹ̀ àwọn ara Gádárénésì, àwọn ọkùnrin méjì ẹlẹ́mìí-èṣù ti inú ibojì wá pàdé rẹ̀ Wọn rorò gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò le kọjá ní ọ̀nà ibẹ̀ Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá tí ń jẹ̀ ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn díẹ̀ sí wọn Àwọn ẹ̀mí-èsú náà bẹ̀ Jésù wí pé, Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ máa lọ! Nígbà tí wọn sì jáde, wọn lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì wò ó, gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì rọ́ gììrì sọ̀ kalẹ̀ bèbè-odò bọ́ sínú òkun, wọ́n sì ṣègbé nínú omi Àwọn ẹni tí ń ṣọ wọn sì sá, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí ìlú, wọ́n ròyìn ohun gbogbo, àti ohun tí a ṣe fún àwọn ẹlẹ́mìí-èṣù Nígbà náà ni gbogbo ará ìlú náà sì jáde wá í pàdé Jésù Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́, kí ó lọ kúrò ní agbégbé wọn Jésù Mú Arọ Láradá Jésù bọ́ sínú ọkọ̀, ó sì rékọjá òdo lọ sí ìlú abínibí rẹ̀ Àwọn ọkùnrin kan gbé arọ kan tọ̀ ọ́ wá lórí ẹní rẹ̀ Nígbà tí Jésù rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí fún arọ náà pé, Ọmọ tújúká, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́ Nígbà yìí ni àwọn olùkọ́ òfin wí fún ara wọn pé, Ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀-òdì! Jésù sì mọ̀ èrò inú wọn, ó wí pé, Nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe ń ro búburú nínú yín Èwo ni ó rọrùn jù láti wí pé, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ tàbí wí pé, Dìde, kí o sì máa rìn Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ni Ó sì wí fún arọ náà pé, Dìde, sì gbé ẹní rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ Ọkùnrin náà sì dìde, ó sì lọ ilé rẹ̀ Nígbà tí ìjọ ènìyàn rí í ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, ti ó fi irú agbára báyìí fún ènìyàn Bí Jésù sì ti ń rékọjá láti ibẹ̀ lọ, o rí ọkùnrun kan ti à ń pè ní Mátíù, ó jókòó ní ibùdó àwọn agbowó-òde, ó sì wí fún un pé, Máa tọ̀ mí lẹ́yìn, Mátíù sì dìde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Ó sì ṣe, bí Jésù tí jókòó ti ó ń jẹun nínú ilé Mátíù, sì kíyèsí i, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-òde àti ẹlẹ́sẹ̀ wá, wọ́n sì bá a jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Nígbà tí àwọn Farisí sì rí i, wọ́n wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,  Èé ṣe tí Olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó-òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀ jẹun pọ̀ Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù gbọ́ èyí, ó wí fún wọn pé, Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá Ṣùgbọ́n ẹ lọ kọ́ bí a ti mọ̀ èyí sí Àánú ni èmi ń fẹ́, kì í ṣe ẹbọ nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́sẹ̀ Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù tọ̀ ọ́ wá láti béèrè wí pé, Èé ṣe tí àwa àti àwọn Farisí fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀ Jésù sì dáhùn pé, Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa sọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀ Kò sí ẹni tí í fi ìrépé aṣọ tutun lẹ ògbólògbó ẹ̀wù nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí titun sínú ògbólògbó ìgò-awọ bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-àwọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-àwọ á sì ṣègbé Ṣùgbọ́n ọtí titun ni wọn í fi sínú ìgò-àwọ tuntun àwọn méjèèjì a ṣì ṣe dédé Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsí i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, Ọmọbìnrin mi kú nísinsìn yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè Jésù dìde ó sì bá a lọ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Ṣì kíyèsí i, obìnrin kan ti ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá, ó wá lẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ Nítorí ó wí nínú ara rẹ̀ pé, Bí mo bá sáà le fi ọwọ́ kan ìsẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá Nígbà tí Jésù sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dà A sì mú obìnrin náà lára dà ni wákàtí kan náà Nígbà tí Jésù sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afọnfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń paríwó Ó wí fún wọn pé, Ẹ máa lọ nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà Ṣùgbọ́n nígbà tí a ti àwọn ènìyàn jáde, ó wọ ilé, ó sì fà ọmọbìnrin náà ní ọwọ́ sókè bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin náà sì dìde Òkìkí èyí sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà Nígbà tí Jésù sì jáde níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n ń kígbe sókè wí pé, Ṣàánú fún wa, ìwọ ọmọ Dáfídì Nígbà tí ó sì wọ̀ ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ wá, Jésù bi wọ́n pé, Ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo le ṣe èyí Wọn sì wí fún un pé, Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ìwọ lè ṣe é Ó sì fi ọwọ́ bà wọ́n ní ojú, ó wí pé, Kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín Ojú wọn sì là Jésù sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi, wí pé, Kíyèsí i, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kan ki o mọ̀ nípa èyí Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n lọ, wọ́n ròyìn rẹ̀ yí gbogbo ìlú náà ká Bí wọ́n tí ń jáde lọ, wò ó wọ́n mú ọkùnrin odi kan tí ó ní ẹ̀mí-èṣù tọ Jesu wá Nígbà tí a lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin tí ó ya odi sì fọhùn Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, wọ́n wí pé, A kò rí irú èyí rí ní Ísírẹ́lì Ṣùgbọ́n àwọn Farisí wí pé, Agbára olórí àwọn ẹ̀mí-èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí-èṣù jáde Jésù sì rìn yí gbogbo ìlú ńlá àti ìletò ká, ó ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìyìn rere ìjọba, ó sì ń ṣe ìwòsàn àrùn àti gbogbo àìsàn ní ara àwọn ènìyàn Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àánú wọn ṣe é, nítorí àárẹ̀ mú wọn, wọn kò sì rí ìrànlọ́wọ́, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan Nítorí náà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀ Ìdájọ́ Tí Ó Lòdì Sí Samáríà Àti Jérúsálẹ́mù Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Míkà ará Mórésétì wá ní àkókò ìjọba Játamù, Áhásì, àti Heṣekáyà, àwọn ọba Júdà nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaríà àti Jérúsálẹ́mù Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, fétísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, kí Olúwa alààyè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, Olúwa láti inú tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ̀ wá Wò ó! Olúwa ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀ Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀, àwọn àfonífojì yóò sì pín yà, bí idà níwájú iná, bí omi tí ó ń ṣàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Nítorí ìré-òfin-kọjá Jákọ́bù ni gbogbo èyí, àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì Kí ni ìré-òfin-kọjá Jákọ́bù Ǹjẹ́ Samaríà ha kọ Kí ni àwọn ibi gíga Júdà Ǹjẹ́ Jérúsálẹ́mù ha kọ Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaríà bí òkítì lórí pápá, bí ibi ti à ń lò fún gbíngbin àjàrà Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀sẹ̀ rẹ̀ palẹ̀ Gbogbo àwọn ère fífín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹ́ḿpìlì rẹ̀ ni a ó fi iná sun Èmi yóò sí pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà, gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà Nítorí èyí, èmi yóò sì sunkún, èmi yóò sì pohùnréré ẹkún èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ihòòhò Èmi yóò ké bí akátá, èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlewòtán ó sì ti wá sí Júdà Ó sì ti dé ẹnu bodè àwọn ènìyàn mi, àní sí Jérúsálẹ́mù Ẹ má ṣe sọ ní Gátì ẹ má ṣe sunkún rárá Ní ilẹ̀ Bẹti-ófírà mo yí ara mi nínú eruku Ẹ kọjá lọ ni ìhòòhò àti ni ìtìjú, ìwọ tí ó ń gbé ni Sáfírì Àwọn tí ó ń gbé ni Sáánánì kì yóò sì jáde wá Bétésélì wà nínú ọ̀fọ̀ A ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin Nítorí àwọn tí ó ń gbé ni Márátì ń retí ire, Ṣùgbọ́n ibi sọ̀kalẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí ẹnu bodè Jérúsálẹ́mù Ìwọ olùgbé Lákísi, dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin Síónì, nítorí a rí ìré-òfin-kọjá Ísírẹ́lì nínú rẹ̀ Nítorí náà ni ìwọ ó ṣe fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún Mórésétígátì Àwọn ilé Ákísíbì yóò jẹ́ ẹlẹ̀tàn sí àwọn ọba Ísírẹ́lì Èmi yóò sì mú àrólé kan wá sórí rẹ ìwọ olùgbé Máréṣà Ẹni tí ó jẹ́ ogo Ísírẹ́lì yóò sì wá sí Ádúlámù Fá irun orí rẹ nínú ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ aláìlágbára, sọ ra rẹ̀ di apárí bí ẹyẹ igún, nítorí wọn yóò kúrò lọ́dọ̀ rẹ lọ sí ìgbèkùn Èrò Ènìyàn Àti Ti Ọlọ́run Ègbé ni fún àwọn tí ń gbérò àìṣedéédéé tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn! Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jáde nítorí ó wà ní agbára wọn láti se é Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n, àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ lára àni ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀ Nítorí náà, Olúwa wí pé Èmi ń gbérò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí, nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́, nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà wọn yóò sì pohùn réré ẹkún kíkorò pé Ní kíkó a ti kó wọn tán Olúwa ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi! Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́   Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkan kan nínú ìjọ Olúwa , tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò Ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀lẹ̀, ni àwọn Wòlíì wọn wí Ẹ má ṣe ṣọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí kí ìtìjú má ṣe le bá wa Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jákọ́bù Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nì wọ̀nyí Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rere fún ẹni tí ń rìn déédé bí Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìde bí ọ̀tá sí mi Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀ kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu, bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun Ẹ̀yin sì lé obìnrin àwọn ènìyàn mi kúrò nínú ilé ayọ̀ wọn, ẹ̀yin sì ti gba ògo mi, kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn láéláé Ẹ dìde, kí ẹ sì máa lọ! Nítorí èyí kì í ṣe ibi ìsinmi yín, nítorí tí a ti sọ ọ́ di àìmọ́ yóò pa yín run, àní ìparun kíkorò Tí òpùrọ́ àti ẹlẹ́tàn bá wà tí wọ́n sì wí pé, Èmi yóò sọ tẹ́lẹ̀ fún ọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wáìnì àti bíà, òun ni yóò tilẹ̀ ṣe wòlíì àwọn ènìyàn wọ̀nyí! Èmi yóò kó gbogbo yín jọ, ìwọ Jákọ́bù Èmi yóò gbá ìyókù Ísírẹ́lì jọ Èmi yóò kó wọn jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú agbo ẹran, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nínú agbo wọn, ibẹ̀ yóò sì pariwo nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn Ẹni tí ó ń fọ ọ̀nà yóò lọ sókè níwájú wọn Wọn yóò fọ láti ẹnu-bodè, wọn yóò sì jáde lọ Àwọn ọba wọn yóò sì kọjá lọ níwájú wọn, Olúwa ni yóò sì ṣe olórí wọn Bíbá Àwọn Olórí Àti Àwọn Wòlíì Wí Nígbà náà, ni mo wí pé, Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jákọ́bù, ẹ̀yin alákòóso ilé Ísírẹ́lì Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ha ṣe láti mọ òdodo bí Ẹ̀yin tí ó kórìíra ire, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi Ẹ̀yin tí ẹ fa awọ-ẹran ara àwọn ènìyàn mi ya kúrò lára wọn àti ẹran-ara wọn kúrò ní egungun wọn Àwọn tí ó jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi, wọn sì bọ́ awọ-ara wọn kúrò lára wọn Wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́ Wọn sì gée sí wẹ́wẹ́ bí ẹran inú ìkòkò, bí ẹran inú òdù Nígbà náà ni wọn yóò kígbe sí Olúwa , Ṣùgbọ́n òun kì yóò dá wọn lóhùn Ní àkókò náà ni òun yóò fi ojú rẹ̀ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, nítorí ibi tí wọ́n ti ṣe Báyìí ni Olúwa wí Ní ti àwọn Wòlíì tí ń sí àwọn ènìyàn mi lọ́nà, tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ, wọn yóò kéde àlàáfíà Ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu, wọn yóò múra ogun sí i Nítorí náà òru yóò wá sórí yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan, òkùnkùn yóò sì kùn fún yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì lè ṣọ tẹ́lẹ̀ Oòrùn yóò sì yọ lórí àwọn wòlíì ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn Ojú yóò sì ti àwọn Wòlíì àwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn, nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mi Olúwa , láti sọ ìré-òfin-kọjá Jákọ́bù fún-un, àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì fún-un Gbọ́ ẹ̀yin olórí ilé Jákọ́bù, àti ẹ̀yin alákòóso ilé Ísírẹ́lì, tí ó kórìíra òdodo tí ó sì yí òtítọ́ padà Tí ó kọ́ Síónì pẹ̀lú ìtàjẹ̀sílẹ̀, àti Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ìwà búrurú Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó-ọ̀yà àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nítorí owó Ṣíbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé Olúwa , wọ́n sì wí pé, Ní tòótọ́, Olúwa wà pẹ̀lú wa! Ibi kan kì yóò bá wa Nítorí náà, nitorí tiyín, ni a ó ṣe ro Síónì bí oko, Jérúsálẹ́mù yóò sì di ebè àti òkè tẹ́ḿpìlì bí i ibi gíga igbo Èrò Ní ọjọ́ ìkẹyìn a ó fi òkè ilé Olúwa lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa , àti sí ilé Ọlọ́run Jákọ́bù Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwa ó sì máa rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀ Nítorí láti Síónì ni òfin yóò ti jáde wá, àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti Jérúsálẹ́mù Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jínjìn réré Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtùlẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ nípa ogun jíjà mọ́ Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnikan kì yóò sì dẹ́rù bà wọ́n, nítorí Olúwa àwọn ọmọ ogun ti sọ̀rọ̀ Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn, olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa láé àti láéláé Ní ọjọ́ náà, ni Olúwa wí, Èmi yóò kó àwọn arọ jọ èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ, àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tó kù, èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára Olúwa yóò sì jọba lórí wọn ní òkè-ńlá Síónì láti ìsinsìn yìí lọ àti títí láéláé Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn, odi alágbára ọmọbìnrin Síónì, a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí Má a yí síhìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora, ìwọ obìnrin Síónì, bí ẹni tí ń rọbí, nítorí nísinsìn yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú, ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó Ìwọ yóò lọ sí Bábílónì níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ Wọ́n sì wí pé, Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́, Ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Síónì! Ṣùgbọ́n wọn kò mọ èrò inú Olúwa Bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn, nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Síónì, nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin, èmi yóò sì sọ pátakó rẹ̀ di idẹ ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orilẹ̀-èdè pátapáta Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwa àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo aye Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Olùgbàlà Láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ, ìwọ ọmọbìnrin ọ̀wọ́ ogun, nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Ísírẹ́lì ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kékeré láàrin àwọn ẹ̀yà Júdà, nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí Ísírẹ́lì yóò ti jáde tọ̀ mí wá, ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́, láti ìgbà láéláé Nítorí náà Ísírẹ́lì yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá títí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí, àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padà láti dara pọ̀ mọ́ àwọn Ísírẹ́lì Òun yóò sì dúró, yóò sì máa ṣe Olùsọ́-àgùntàn àwọn agbo-ẹran rẹ̀ ní agbára Olúwa , ní ọláńlá orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ Wọn yóò sì wà láìléwu, nítorí nísinsin yìí ni títóbi rẹ yóò sì dé òpin ayé Òun yóò sì jẹ́ àlàáfíà wọn Nígbà tí àwọn Ásíríà bá gbógun sí ilẹ̀ wa tí wọ́n sì ń yan lórí odi alágbára wa, nígbà náà ni a ó gbé olúsọ́-àgùntàn méje dìde sí i, àti olórí ènìyàn mẹ́jọ Wọn yóò sì fi idà pa ilẹ̀ Ásíríà run, àti ilẹ̀ Nímíródù pẹ̀lú idà tí a fà Òun yóò sì gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà nígbà tí wọn bá gbógun ti ilẹ̀ wa tí wọ́n sì tún yan wọ inú ìpínlẹ̀ wa Ìyòókù Jákọ́bù yóò sì wà láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bí ìrì látí ọ̀dọ̀ Olúwa wa, bí ọ̀wàrà òjò lórí koríko, tí kò gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn tàbí kò dúró de àwọn ọmọ ènìyàn Ìyòókù Jákọ́bù yóò sì wà láàrin àwọn aláìkọlà ní àárin àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, bí i kìnnìún láàrin àwọn ẹranko inú igbó, bí i ọmọ kìnnìún láàrin agbo àgùntàn, èyí tí ó máa ń fàá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tí ó sì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè gbà á là A ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀ sì ni a ó parun Ní ọjọ́ náà, ni Olúwa wí, Èmi yóò pa àwọn esin rẹ̀ run kúrò láàrin rẹ èmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run Èmi yóò sì pa ilẹ̀ ìlú-ńlá rẹ̀ run, èmi ó sì fa gbogbo ibi gíga rẹ̀ ya Èmi yóò gé ìwà-àjẹ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, ìwọ kì yóò sì ní aláfọ̀ṣẹ mọ́ Èmi yóò pa àwọn ère fífín rẹ̀ run, àti ọwọ́n rẹ̀ kúrò láàrin rẹ̀ ìwọ kì yóò sì le è foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mọ́ Èmi yóò fa òpó òrìṣà rẹ tu kúrò láàrin rẹ̀, èmi yóò sì pa ìlú ńlá rẹ̀ run Èmi yóò gbẹ̀san ní ìbínú àti ìrunú lórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ti tẹríba fún mi Ọlọ́run Pe Ísírẹ́lì Níjà Ẹ fi etí sí ohun tí Olúwa wí Dìde dúró, bẹ ẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ níwájú òkè ńlá sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèkéé gbọ́ ohun tí ó fẹ́ wí Gbọ́, ìwọ òkè ńlá, ẹ̀sùn Olúwa gbọ́, ìwọ ìpìlẹ̀ ilé ayerayé Nítorí Olúwa ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wíjọ́ òun yóò sì bá Ísírẹ́lì rojọ́ Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín Àti nínú kí ni mo ti dá yin lágara Dá mi lóhùn Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá Mo rán Mósè láti darí yín bákan náà mo rán Árónì àti Míríámù ṣíwájú rẹ̀ Ìwọ ènìyàn mi, rántí ohun tí Bálákì ọba Móábù gbèrò àti ohun tí Bálámù ọmọ Béórì dáhùn Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣítímù dé Gígálì, kí ìwọ ba le mọ òdodo Olúwa Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú Olúwa tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan Ǹjẹ́ Olúwa yóò ní inúdídùn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbò, tàbí sí ẹgbẹgbàárùn-ún ìṣàn òróró Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi, èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi Ó ti fi hàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí í ṣe rere, àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ Ṣùgbọ́n láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú, àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀ Gbọ́! Ohùn Olúwa kígbe sí ìlú ńlá náà, ọlọgbọ́n yóò sì rí orúkọ rẹ̀! Ẹ gbọ́ ọ̀pá àti Ẹni náà tí ó yàn án Ǹjẹ́ ìṣúra ìwà búrurú ha wà ní ilé ènìyàn búrurú ṣíbẹ̀, àti òṣùwọ̀n àìkún tí ó jẹ́ ohun ìbínú Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́ pẹ̀lú òṣùwọ̀n búrurú, pẹ̀lú àpò òṣùwọ̀n ẹ̀tàn Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìṣàn ní lílù ọ́, láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ Ìwọ yóò jẹun ṣùgbọ́n kì yóò yó ìyàn yóò wà láàrin rẹ Ìwọ yóò kó pamọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lò làìléwu, nítorí ohun tí ìwọ kò pamọ́ ni èmi yóò fi fún idà Ìwọ yóò gbìn ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kórè ìwọ yóò tẹ ólífì, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò fi òróró rẹ̀ kún ara rẹ ìwọ yóò tẹ èso àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò mu wáìnì Nítorí tí ìwọ ti pa òfin Omiri mọ́, àti gbogbo iṣẹ́ ilé Áhábù, tí ó sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn, nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ fún ìparun àti àwọn ènìyàn rẹ fún ìfiṣe ẹlẹ́yà ìwọ yóò sì ru ẹ̀gàn àwọn ènìyàn mi Ìrora Ísírẹ́lì Ègbé ni fún mi! Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ, ìpèsè ọgbà àjàrà kò sì sí odidi àjàrà kankan láti jẹ, kò sì sí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí Àwọn olódodo sì ti kúrò ní ilẹ̀ náà, kò sì sí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù tí ó jọ olóòótọ́ gbogbo wọn sì ń purọ́ ní dídúró nítorí ìtàjẹ̀sílẹ̀, olúkúlùkù wọ́n sì ń fi àwọ̀n de arákùnrin rẹ̀ Ọwọ́ wọn méjèèje ti múra tán láti ṣe búburú àwọn alákóso ń bèèrè fún ẹ̀bùn, àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́, gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀ Ẹni tí ó sàn jùlọ nínú wọn sì dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ burú ju ẹ̀gún ọgbà lọ Ọjọ́ àwọn olùsọ́ rẹ̀ ti dé, àti ọjọ́ tí Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ wò Nísinsin yìí ní àkókò ìdààmú wọn Ẹ má ṣe gba ọ̀rẹ́ kan gbọ́ ẹ má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé amọ̀nà kankan Pa ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ fún ẹni tí ó sùn ní oókan-àyà rẹ Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀ ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀, aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀, ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀ Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní wòye ní ìrètí sí Olúwa , Èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi Má ṣe yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi Bí mó bá ṣubú, èmi yóò dìde Nígbà tí mo bá jókòó sínú òkùnkùn Olúwa yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi Nítorí èmi ti dẹ́sẹ̀ sí i, Èmi yóò faradà ìbínú Olúwa , títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò, tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀ èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀ Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé, Níbo ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wà Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀ nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ òpópó Ọjọ́ tí a ó mọ odi rẹ yóò dé, ọjọ́ náà ni àṣẹ yóò jìnnà réré Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ láti Ásíríà àti ìlú ńlá Éjíbítì àní láti Éjíbítì dé Yúfúrátè láti òkun dé òkun àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá Ilẹ̀ náà yóò di ahoro fún àwọn olùgbé ìnú rẹ̀, nítorí èso ìwà wọn Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ, èyí tí ó ń dáágbé nínú igbó ní àárin kámẹ́lì Jẹ̀ kí wọn jẹun ní Básánì àti Gílíádì bí ọjọ́ ìgbàànì Bí i ọjọ́ tí ó jáde kúrò ní Éjíbítì wá, ni èmi yóò fi ohun-ìyanu hàn án Orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú yóò sì tì wọ́n, nínú gbogbo agbára wọn Wọn yóò fi ọwọ́ lé ẹnu wọn, etí wọn yóò sì di Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò, wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló Wọn yóò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀ Ta ni Ọlọ́run bí ì rẹ̀, ẹni tí ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn, tí ó sì fojú fo ìrékọjá èyí tó kù ìní rẹ̀ Kì í dúró nínú ìbínú rẹ̀ láéláé nítorí òun ní inú dídùn sí àánú Òun yóò tún padà yọ́nú sí wa òun yóò tẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀, yóò sì fa gbogbo àìṣedéédéé wa sínú ibú òkun Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jákọ́bù ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Ábúráhámù, bí ìwọ se búra fún àwọn baba wa láti ọjọ́ ìgbà a nì Jòhánù Onítẹ̀bọmi Tún Ọ̀nà Se Sílẹ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ ìyìnrere nípa Jésù Kírísítì, Ọmọ Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Àìṣáyà pé Èmi yóò ran oníṣẹ́ mí ṣíwájú rẹ, Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe Ohùn ẹnìkan tí ń kígbe ní ihà, Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ se ojú-ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́   Jòhánù dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní ihà, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Jùdíà, àti gbogbo ènìyàn Jerúsálémù jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọmi ni odò Jọ́dánì, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn Jòhánù sì wọ ẹ̀wù tí a fi irun ràkúnmí hun Ó sì lo ìgbànú awọ Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹṣẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú Èmi ń fi omi se ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ se ìtẹ̀bọmi yín Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jésù ti Násárẹ́tì ti Gálílì jáde wá, a sì ti ọwọ́ Jòhánù tẹ̀ Ẹ bọmi ní odò Jọ́dánì Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jésù ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó sí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọkalẹ̀ lé E lórí Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ìwọ ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi Lẹ́sẹ̀kan-náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jésù sí ihà, Ó sì wà níbẹ̀ fún ogójì ọjọ́ A sì fi Í lé Èṣù lọ́wọ́ láti dán an wò Àwọn ańgẹ́lì sì wá ṣe ìtọ́jú Rẹ̀ Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Hẹ́rọ́dù ti fi Jòhánù sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jésù lọ sí Gálílì, ó ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba Ọlọ́run Ó sì kéde wí pé, Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dèdè Ẹ yípadà kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́ Ní ọjọ́ kan, bí Jésù ti ń rìn létí òkun Gálílì, Ó rí Ṣímónì àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé Apẹja ni wọ́n Jésù sì ké sí wọn wí pé, Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn Bí Ó sì ti rìn ṣíwájú díẹ̀, ní etí òkun, Ó rí Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè nínú ọkọ̀ wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sébédè baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tẹ̀lé e Lẹ́yìn náà, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapanámù, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsimi, ó lọ sínú sínágọ́gù, ó sì ń kọ́ni Ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kóni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn Ní àsìkò náà gan-an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú sínágọ́gù wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé, Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jésù ti Násárẹ́tì Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run! Jésù si bá a wí, ó wí pé, Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúro lára rẹ̀ Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e sánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sọ láàrin ara wọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ Wọ́n béèrè pẹ̀lú ìgbóná ara, pé, Kí ni èyí Irú ẹ̀kọ́ titun wo ni èyí Ó ń fi agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀ Ìròyìn nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbégbé Gálílì Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú sínágọ́gù, wọ́n lọ pẹ̀lú Jákọ́bù àti Jòhánù sí ilé Símónì àti Ańdérù Ìyá ìyàwó Símónì tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jésù nípa rẹ̀ Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde lójú kan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí òòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà Jésù sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú aláìsàn sàn Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í se Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jésù nìkan jáde lọ sí ihà kan, láti lọ gbàdúrà Símónì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, Gbogbo ènìyàn ń wá ọ! Jésù sì dáhùn wí pé, Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbégbé Gálílì, ó ń wàásù nínú àwọn sínágọ́gù Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀ Ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìmúláradà Ó wí pé, Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi láradá Jésù kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, Èmí fẹ́ Di mímọ́ Lójúkan-náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn Jésù sì kìlọ̀ fún un gidigidi Ó wí pé, Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mósè pa láṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a múláradá Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkì, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀ Nítorí èyí, Jésù kò sì le wọ ìlú ní gba-n-gba mọ́, ṣùgbọ́n ó wà lẹ́yìn odi ìlú ní ihà Ṣíbẹ̀, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo Ìkọ̀sílẹ̀ Nígbà náà, Jésù kúrò ní Kapanámù Ó gba gúsù wá sí agbègbè Jùdíà, títí dé ìlà oòrùn odò Jọ́dánì Bí i ti àtẹ̀yìnwá, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀ Ó sì kọ́ wọn pẹ̀lú bí i ìṣe rẹ̀ Àwọn Farisí kan tọ̀ ọ́ wá, láti dán an wò Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Ǹjẹ́ ó ha tọ̀nà fún ènìyàn láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Kí ni Mósè pa láṣẹ fún un yín nípa ìkọ̀sílẹ̀ Wọ́n dáhùn pé, Mósè yọ̀ǹda ìkọ̀sílẹ̀ Ohun tí ọkùnrin náà yóò ṣe ni kí ó fún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, lẹ́yìn èyí, ààyè wà láti kọ obìnrin náà sílẹ̀ Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn, ó sì wí pé, Mósè kọ òfin yìí fun un yín nítorí ẹ jẹ́ ọlọ́kàn líle Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì faramọ́ aya rẹ̀ Òun àti ìyàwó rẹ̀ yóò di ara kan náà Nítorí náà, wọn kì í tún ṣe méjì mọ́ bí kò ṣe ẹyọ ọ̀kan ṣoṣo Nítorí náà ohun ti Ọlọ́run bá sọ dọ̀kan, ki ẹnikẹ́ni máa ṣe yà wọ̀n Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù nìkan wà nínú ilé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n tún béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ohun kan náà Jésù túbọ̀ ṣe àlàyé fún wọn pé, Nígbà tí ọkùnrin kan bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tí ó bá sì fẹ ẹlòmíràn, irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà sí obìnrin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé níyàwó Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí obìnrin kan bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì fẹ́ ọkùnrin mìíràn, irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tọ Jésù wá kí ó lè súre fún wọn Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kígbe mọ́ àwọn tí ń gbé àwọn ọmọdé wọ̀nyí bọ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ yọ Jésù lẹ́nu rárá Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Nítorí náà, ó sọ fún wọn pé, Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé kékeré wá sọ́dọ̀ mi Ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun nítorí pé irú wọ́n ni ìjọba Ọlọ́run Mo ń sọ òótọ́ fún un yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti mọ̀, pé, ẹni tí kò bá wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bi ọmọ kékeré, a kì yóò fún un láàyè láti wọ ìjọba rẹ̀ Nígbà náà, Jésù gbé àwọn ọmọ náà lé ọwọ́ rẹ̀, ó gbé ọwọ́ lé orí wọn Ó sì súre fún wọn Bí Jésù ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò kan, ọkùnrin kan sáré wá sọ́dọ̀ rẹ̀ Ó sì kúnlẹ̀, ó béèrè pé, Olùkọ́ rere, kí ni èmi yóò ṣe láti jogún ìyè àìnipẹ̀kun Jésù béèrè pé, Arákùnrin, Èéṣe tí o fi ń pè mí ní ẹni rere Ẹni rere kan kò sí Ọlọ́run nìkan ni ẹni rere Ìwọ mọ àwọn òfin bí i Má ṣe pànìyàn, má ṣe panṣágà, má ṣe jalè, má ṣe purọ́, má ṣe rẹ́ ọmọnìkejì jẹ, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ Ọkùnrin náà dáhùn pé, Olùkọ́, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń ṣe láti ìgbà èwe mi wá Jésù wò ó tìfẹ́tìfẹ́ Ó wí fún un pé, Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan ló kù fún ọ láti ṣe, lọ nísinsìn yìí, ta gbogbo nǹkan tí o ní, kí o sì pín owó náà fún àwọn aláìníìwọ yóò sì ni ìsura ní ọ̀run, sì wá, gbe àgbélébú, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn Nígbà tí ọkùnrin yìí gbọ́ èyí, ojú rẹ̀ korò, ó sì lọ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí pé ó ní ọrọ̀ púpọ̀ Jésù wò ó bí ọkùnrin náà ti ń lọ Ó yípadà, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Àní, ohun ìṣòro ni fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run! Ọ̀rọ̀ yìí ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu Jésù tún sọ fún wọn pé, Ẹ ẹ̀yin ènìyàn yóò tí ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ kan láti wọ ìjọba ọ̀run Ẹnu túbọ̀ ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sí i Wọ́n béèrè wí pé, Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni nínú ayé ti ó lè ní ìgbàlà Jésù wò wọ́n ó sì wí fún wọn pé, Ènìyàn ní èyí kò se é ṣe fún ṣùgbọ́n kì í ṣe fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ni síṣe fún Ọlọ́run Nígbà náà ni Pétérù kọjú sí Jésù, ó wí pé, Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Jésù dáhùn pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ohúnkóhun sílẹ̀ bí ilé, tàbí àwọn arákùnrin, tàbí àwọn arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí baba, tàbí àwọn ọmọ tàbí ohun ìní, tí a kì yóò fún padá ní ọgọọgọ́rùn-ún àwọn ilé, tàbí arákùnrin, tàbí arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí ọmọ, tàbí àti ilẹ̀, tàbí bí inúnibini tilẹ̀ wà Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ tirẹ̀ ní ayé yìí àti pé ní ayé tó ń bọ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú ni yóò kẹ́yìn, àwọn tí ó sì kẹ́yìn yóò síwájú Nísinsìn yìí, wọ́n wà lójú ọ̀nà sí Jerúsálémù Jésù sì ń lọ níwájú wọn, bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti ń tẹ̀lé e, ìbẹ̀rù kún ọkàn wọn Ó sì tún mú àwọn méjìlá sí apá kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ohun gbogbo tí a ó ṣe sí i fún wọn Ó sọ fún wọn pé, Awa ń gòkè lọ Jerúsálémù, a ó sì fi Ọmọ-Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ òfin lọ́wọ́ Wọn ni yóò dá lẹ́bi ikú Wọn yóò sì fà á lé ọwọ́ àwọn aláìkọlà Wọn yóò fi se ẹlẹ́yà, wọn yóò tutọ́ sí ní ara, wọn yóò nà pẹ̀lú pàsán wọn Wọn yóò sì pa, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò tún jíǹde Lẹ́yìn èyí, Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè wá sọ́dọ̀ Jésù Wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, wọ́n wí pé, Olùkọ́, inú wa yóò dùn bí ìwọ bá lè ṣe ojú rere ohunkóhun tí a bá béèrè fún wa Jésù béèrè pé, Kí ni Ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi ó ṣe fún un yín Wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé, Jẹ́ kí ọ̀kan nínú wa jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ẹnikejì ní ọwọ́ òsì nínú ògo rẹ! Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn pé, Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè! Ṣe ẹ lè mu nínú ago kíkorò tí èmi ó mú tàbí a lè bamitíìsì yín pẹ̀lú irú ìbamitíìsì ìjiyà tí a ó fi bamitíìsì mi Àwọn méjèèjì dáhùn pé, Àwa pẹ̀lú lè ṣe bẹ́ẹ̀ Jésù wí fún wọn pé, Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó mu ago ti èmi yóò mu, àti bamitíìsímù tí a sí bamitíìsì mi ni a ó fi bamitíìsì yín, ṣùgbọ́n láti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní ọwọ́ ọ̀sì mi kì ì ṣe ti èmi láti fi fún ni bí kò ṣe fún àwọn ẹni tí a ti pèṣè rẹ̀ sílẹ̀ fún Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù gbọ́ ohun tí Jákọ́bù àti Jòhánù béèrè, wọ́n bínú Nítorí ìdí èyí, Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn Ṣùgbọ́n láàrin yín ó yàtọ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di olórí nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́ Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ di aṣáájú nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́ gbogbo yín Nítorí, Èmi, Ọmọ ènìyàn kò wá sí ayé kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún mi, ṣùgbọ́n láti lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, àti láti kú fún ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn Wọ́n dé Jẹ́ríkò, bí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fẹ́ kúrò ní ìlú Jẹ́ríkò, ọkùnrin afọ́jú kan, Bátíméù, ọmọ Tíméù jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ó ń sagbe Nígbà tí Bátiméù gbọ́ pé Jésù ti Násárẹ́tì wà nítòsí, o bẹ̀rẹ̀ sí kígbe lóhùn rara pé, Jésù ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi Àwọn tó wà níbẹ̀ kígbe mọ́ ọn pé, Pa ẹnu rẹ mọ́ Ṣùgbọ́n dípò kí ó pa ẹnu mọ́, ṣe ló ń kígbe lóhùn rara pé, Jésù ọmọ Dáfídì ṣàánú fún mi Nígbà tí Jésù gbọ́ igbe rẹ̀, ó dẹṣẹ̀ dúró lójú-ọ̀nà, ó sì wí pé, Ẹ pè é kí ó wá sọ́dọ̀ mi Nítorí náà wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n wí pé, Tújúká!, dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ! Ó ń pè ọ́ Lẹ́sẹ̀kan-náà, Bátíméù bọ́ aṣọ rẹ̀ sọnù, ó fò sókè, ó sì wá sọ́dọ̀ Jésù Jésù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Kí ni ìwọ fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún ọ Afọ́jú náà dáhùn pé, Rábì, jẹ́ kí èmi ki o ríran Jésù wí fún un pé, Má a lọ, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá Lẹ́ṣẹ̀kẹṣẹ̀, ọkùnrin afọ́jú náà ríran ó sì ń tẹ̀lé Jésù lọ ní ọ̀nà Fífi Ayọ̀ Wọlé Bí wọ́n ti súnmọ́ Bẹ́tífágè àti Bẹ́tanì ní ẹ̀yìn odi ìlú Jerúsálémù, wọ́n dé orí òkè ólífì Jésù rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ṣíwájú Ó pàṣẹ fún wọn pé, Ẹ lọ sí abúlé tó wà lọ́hùn-ún nì Nígbà tí ẹ bá sì wọlé, ẹ̀yin yóò rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a so mọ́lẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ì tí i gùn rí Ẹ tú u, kí ẹ sì mú wá síhìn-ín Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, Kí ló dé tí ẹ fi ń se èyí Ẹ sọ fún un pé, Olúwa ní í fi ṣe, yóò sì dá a padà síbí láìpẹ́ Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà lọ bí ó ti rán wọn Wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó dúró ní ìta gbangba tí a so mọ́lẹ̀ Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, Kí ni ẹ̀ ń ṣe, È ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì wọ̀nyí sọ ohun tí Jésù ní kí wọ́n sọ Nítorí náà àwọn ènìyàn náà yọ̀ǹda fún wọn láti mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lọ Wọ́n mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jésù wá Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì bọ́ ẹ̀wù wọn, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún Jésù láti jókòó lórí rẹ̀ Nígbà náà, púpọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ènìyàn tẹ́ àṣọ wọn sójú-ọ̀nà níwájú u rẹ̀ Àwọn mìíràn ju ewéko ìgbẹ́ sílẹ̀ Jésù wà láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn níwájú, lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé, Hòsánà! Olùbùkún ni ẹni náà tí ó ń bọ̀ wà ní orúkọ Olúwa! Olubùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dáfídì, baba wa! Hòsánà lókè ọ̀run! Jésù wọ Jerúsálémù ó sì lọ sí inú tẹ́ḿpílì Ó wo ohun gbogbo yíká fínnífínní Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti sú Ó padà lọ sí Bẹ́tanì pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Bẹ́tanì, ebi ń pa Jésù Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán ti ewé kún orí rẹ̀ Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ bóyá ó léso tàbí kò léso Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀ Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so Lẹ́yìn náà, Jésù pàṣẹ fún igi náà pé, Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀ Nígbà ti wọ́n padà sí Jerúsálémù, ó wọ inú tẹ́ḿpílì Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní lé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbárà wọn síta Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹ́ḿpílì ṣubú Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀ Kò sì gba ẹnikẹ́ni láàyè láti gbé ẹrù ọjà títa wọlé Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, Ṣe a kò ti kọ ọ́ pé  Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi, ní gbogbo òrilẹ̀ èdè Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin gbọ́ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbà èrò bí wọn yóò ti ṣe pa á Wọ́n bẹ̀rù rògbòdìyàn tí yóò bẹ́ sílẹ̀, nítorí tí àwọn ènìyàn ní ìgbóná-ọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀ Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, bí ìṣe wọn, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú Jerúsálémù Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jésù fi bú Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò-tigbòǹgbò Pétérù rántí pé Jésù ti bá igi náà wí Nígbà náà ni ó sọ fún Jésù pé, Rábì, Wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ! Jésù sì dáhùn pé, Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ṣí ìdí, gbé ara rẹ sọ sínú òkun ti kò sí ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n ti ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ ti yín nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì ẹni tí ó ṣẹ̀ yín Baba yín lọ́run yóò dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá dáríjì, Baba yín ti ń bẹ ni ọ̀run kí yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún padà sí Jerúsálémù Bí Jésù ti ń rìn kíri ni tẹ́ḿpílì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn tí ń kọ́ni ni òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Júù wá sọ́dọ̀ rẹ̀ Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Àṣẹ wo ni ó fi ń se nǹkan yìí Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí láti máa ṣe nǹkan wọ̀nyìí Jésù dá wọn lóhùn pé, Èmi yóò sọ fún un yín bí ẹ bá lè dáhùn ìbéèrè mi yìí Ìtẹ̀bọmi Jòhánù láti ọ̀run wa ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn Ẹ dá mi lóhùn! Wọ́n bá ara wọn jíjòrò pé Bí a bá wí pé Ọlọ́run ni ó rán an wá nígbà náà yóò wí pé, nígbà tí ẹ mọ̀ bẹ́ẹ̀, èéṣe tí ẹ kò fi gbà à gbọ Ṣùgbọ́n bí a bá sọ wí pé Ọlọ́run kọ́ ló rán an, nígbà náà àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rẹ̀ rògbòdìyàn Nítorí pé gbogbo ènìyàn ló gbàgbọ́ pé wòlíì gidi ni Jòhánù Nítorí náà, Wọ́n kọjú sí Jésù wọn sì dáhùn pé, Àwa kò mọ̀ Nígbà náà ni Jésù wí pé, Níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò lè dáhùn ìbéèrè mi, Èmi náà kì yóò sọ fún yín àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí Òwe Àwọn Ayálégbé Lẹ́yìn ìgbà tí Jésù pa àwọn olórí ẹ̀sìn lẹ́nu mọ́ ó bẹ̀rẹ̀ síí fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, Ọkùnrin kan dá oko àjàrà kan Ó ṣe ọgbà yì i ká, ó sì gbẹ́ ihò níbi tí omi yóò ti máa jáde fún ìtọ́jú ohun ọ̀gbìn Níkẹyìn, ó gbé oko fún àwọn olùtọ́jú, ó sì lọ ìrìnàjò tí ó jìnnà Lákókò ìkórè, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn tí ń tọ́jú oko tí ó fi sílẹ̀, láti gba ìpín tirẹ̀ wá nínú ohun ọ̀gbìn oko náà Ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ wọnnnì lu ìránṣẹ́ ọkùnrin náà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo Ó sì tún rán ọmọ-ọ̀dọ̀ mìíràn sí wọn Bí àwọn àgbẹ̀ tí tún rí ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó rán sí wọn wọ́n lù ú Àní, wọ́n tilẹ̀ dá ọgbẹ́ sí i lórí, wọn rán an lọ ni ìtìjú Ó sì tún rán òmíràn, èyí n nì wọ́n sì pa, àti ọ̀pọ̀ mìíràn, wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmiran Ìránṣẹ́ kan ṣoṣo ló kù tí Baba olóko kò ì tí ì rán níṣẹ́, èyí ni ọmọ òun tìkárarẹ̀ Níkẹyìn ó ran an sí àwọn àgbẹ̀ náà, pẹ̀lú èrò pé, Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ òun Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ọmọ baba olóko, wọ́n sọ fún ara wọn pé, Ọmọ rẹ̀ ló ń bọ̀ yìí Òun ni yóò jogún oko yìí tí baba rẹ̀ bá kú Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, lẹ́yìn náà oko náà yóò di tiwa Báyìí ni wọ́n mú ọmọ náà tí wọ́n pa á Wọ́n gbé òkú rẹ̀ kúrò nínú oko Kí ni ẹ rò pé baba olóko yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣélẹ́ Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀ Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹṣẹ yìí nínú ìwé mímọ́  Òkúta tí àwọn ọmọ̀lé ti kọ̀ sílẹ̀ òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé Èyí ni iṣẹ́ Olúwa ó sì jẹ́ ìyàlénu lójú tiwa Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olúkọ̀ òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà fẹ́ mú Jésù lákókò náà Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Àwọn ni alágbàtọ́jú búburú nínú ìtàn rẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìhùwàsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ Ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn Farisí pẹ̀lú àwọn kan tí í ṣe ọmọ-ẹ̀yìn Hẹ́rọ́dù wá sọ́dọ̀ Jésù, láti fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, títí yóò fi sọ ohun kan kí wọn lè rí fi mú Bí wọn ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ tìrẹ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni Nísinsin yìí, sọ fún wa, ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Késárì Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un Ṣùgbọ́n Jésù mọ ìwà àgàbàgebè wọn Ó sì wí pé, Èéṣe tí ẹ̀yin fi fi èyí dán mi wo Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀ Wọ́n dáhùn pé, Àwòrán àti orúkọ Késárì ni Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Késárì fún Késárì Ṣùgbọn ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀ Àwọn Ṣadusí tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí kò gbàgbọ́ pé àjíǹde ń bẹ Ìbéèrè wọn ni pé, Olùkọ́, Mósè fún wa ní òfin pé Nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú láìbímọ Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣu obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, láìpẹ́, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ Arákùnrin kẹta tó sú obìnrin yìí lópó tún kú bákan náà láìbímọ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe títí àwọn méjèèje fi kú láìbímọ Ní òpin gbogbo rẹ̀, obìnrin tí a ń wí yìí náà kú Ohun tí a fẹ́ mọ̀ nìyì Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé àwọn arákùnrin méjèèje ló fẹ́ obìnrin náà, ìyàwó o ta ni yóò jẹ́ nínú wọn lọ́jọ́ àjíǹde Jésù dá wọn lóhùn pé, Ìṣòro yín ni wí pé, ẹ kò mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti agbára Ọlọ́run Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn Wọn yóò dàbí àwọn ańgẹ́lì Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Ẹ́kísódù, nípa Mósè àti pápá tí ń jó Ọlọ́run sọ fún Mósè pé, Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetí sílẹ̀ dáadáa sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jésù ti dáhùn dáadáa Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jésù pé, Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ Jésù dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé Gbọ́ Ísírẹ́lì, Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ ọ̀kan náà, Ọlọ́run kan náà sì ni Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní Èkejì ni pé Fẹ ọmọnikejì rẹ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ Olùkọ́ ófin náà dáhùn pé, Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ nípa pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ, àti pé kò sí òmíràn àfi òun nìkan Àti pé, mo mọ bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti fẹ́ ẹ pẹ̀lú gbogbo agbára mi, àti pẹ̀lú pé kí n fẹ́ràn ọmọnìkéjì mi gẹ́gẹ́ bí ara mi, ju kí n rú oríṣiiríṣii ẹbọ lórí i pẹpẹ ilé ìsìn Jésù rí i dájú pé òye ọkùnrin yìí ga, nítorí náà, Jésù sọ fún un pé, Arákùnrin, ìwọ kò jìnà sí à ti dé ìjọba Ọ̀run Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jésù Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn Ọmọ-Ènìyàn nínú tẹ́ḿpílì, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, È é ṣe tí àwọn olùkọ́-òfin fi gbà wí pé Kírísítì náà ní láti jẹ́ ọmọ Dáfídì Nítorí tí Dáfídì tìkárarẹ̀, ti ń ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé  Ọlọ́run sọ fún Olúwa mi Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀ta rẹ di àpótí ìtìṣẹ̀ rẹ   Níwọ̀n ìgbà tí Dáfídì tìkáraarẹ̀ pè é ní Olúwa, Báwo ni ó tún ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀ Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ayọ̀ gbọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ Ó sì wí fún wọn pé nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, Ẹ sọ́ra lọ́dọ̀ àwọn olùkọ́-òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígun rìn kiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọja, àti ibùjókòó ọlá nínú Sínágọ́gù àti ipò ọlá níbi àṣẹ Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígun fún àsehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀ Jésù jókòó kọjú sí àpótí ìṣúra ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i Ṣùgbọn obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ kọ́bọ̀ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdáméjì owó-bàbà kan sínú rẹ̀ Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìì sọ sínú àpótí ìsura ju gbogbo àwọn ìyókù lọ to sọ sínú rẹ lọ Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀ Àwọn Àmì Òpin Ayé Bí Jésù ti ń jáde láti inú tẹ́ḿpìlì ní ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, Olùkọ́, wo ilé ńlá tí ó dára wọ̀nyí Sì wo òkúta tí a ṣe lọ́sọ̀ọ́ lára àwọn ògiri ilé náà Jésù dáhùn pé, Ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí Kì yóò sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀ Bí Jésù ti jókòó níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olífì tí ó rékọjá àfonífojì láti Jerúsálémù, Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù àti Ańdérù wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkòkọ̀ pé, Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ sí tẹ́ḿpílì náà Kí ni yóò sì jẹ àmì nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ Jésù kìlọ̀ fún wọn pé, Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tan yín Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ni orúkọ mi, wọn yóò wí pé, Èmi ni Kírísítì, wọn yóò tan ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ́ Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbọ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà, nítorí irú nǹkan wọ̀nyí kò le ṣe kí ó má ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe ìgbà yìí Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba ilẹ̀ yóò máa jin ni ibi púpọ̀ Ìyàn yóò sì wà níbi gbogbo Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ń bọ̀ níwájú Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyè sára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú tẹ́ḿpìlì wọn Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn gómìnà àti níwájú àwọn ọba pẹ̀lú, nítorí tí ẹ jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìyìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀ èdè kí òpin tó dé Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá mú yín, tí ẹ sì dúró níwájú adájọ́, ẹ má ṣe dààmú nípa ohun tí ẹ ó wí fún ààbò Ẹ ṣáà sọ ohun tí Ọlọ́run bá fi sí yín lọ́kàn Ẹ̀yin kọ́ ní yóò sọ̀rọ̀, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́ Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀ Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣekú pa òbí wọn Àwọn ènìyàn yóò kórira yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà Ṣùgbọ́n nígba tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró ní bí tí kò tọ́, tí a tí ẹnu wòlíì Dáníẹ́lì sọ, nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Jùdíà sá lọ sí orí òkè Kí ẹni ti ń bẹ lórí ilé má ṣe sọkalẹ̀ lọ sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má si ṣe wọ inú rẹ̀, láti mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀ Kí ẹni tí ó wà lóko má ṣe padà ṣẹ́yìn láti wá mú aṣọ rẹ̀ ègbé ní fún àwọn tí ó lóyún, àti fún obìnrin tí ń fún fọ́mọ lọ́mú ní ọjọ́ wọ̀nyí Kí ẹ sì máa gbàdúrà pé kí ìsákúrò nínú ewu yìí má ṣẹlẹ̀ ní àkókò òtútù Nítorí ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì yóò jẹ́ àkókò ìpọ́njú, irú èyí tí kò ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá Ọlọ́run Irú rẹ̀ kò sì ni ṣẹlẹ̀ mọ́ À fi tí Olúwa bá gé àkókò ìjìyà náà kúrú, ẹyọ ẹ̀mí kan ní ayé kì yóò là Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tí Ọlọ́run yàn, ni yóò ṣe dín àwọn ọjọ́ náà kù Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un yín pé, Ẹ wò ó, Kírísítì nìyìí! tàbí, sọ fún un yín pé, Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn-ún nì! Ẹ má ṣe gbà wọ́n gbọ́ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹ́tàn àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tàn àwọn ọmọ Ọlọ́run pàápàá jẹ Nítorí náà, ẹ sọ́ra Mo ti kìlọ̀ fún un yín ṣáájú tó! Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn ìpọ́njú tí mo sọ yìí,  òòrùn yóò sókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ Àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú yóò já lulẹ̀ láti ojú ọ̀run Ṣánmọ̀ àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ yóò wárìrì Nígbà náà ni gbogbo ayé yóò sì rí i tí Èmi Ọmọ-Ènìyàn yóò máa bọ̀ wá láti inú àwọ̀sánmọ̀pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá Nígbà náà ni yóò sì rán àwọn ańgẹ́lì rẹ láti kó àwọn àyànfẹ ní gbogbo ayé jọ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aye láti ìkángun ayé títí dé ìkangun ọ̀run Nísinsin yìí, ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ kan lára igi ọ̀pọ̀tọ́, nígbà tí ẹ̀ka rẹ bá ń yọ titun, tí ó bá sì ń rú ewé, èyí fi hàn pé àkókò ẹ̀rùn ti dé Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí àwọn ohun abàmì wọ̀n-ọn-nì tí mo ti sọ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó súnmọ́ etílé tan, lẹ́yìn ìlẹ̀kùn Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, Iran yìí kì yóò rékọjá títí a ó fi mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹ Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ Àwọn ańgẹ́lì ọ̀run pàápàá kò mọ̀ Àní, èmi pẹ̀lú kò mọ̀ ọ́n Ọlọ́run Baba nìkan ló mọ̀ ọ́n Ẹ máa sọra, Ẹ má ṣe sùn kí ẹ sì máa gbàdúrà nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà ní ó àkókò ná yóò dé Ohun tí a lè fi bíbọ̀ mi wé ni ọkùnrin kan tí ó lọ sí ìrìnàjò sí orílẹ̀ èdè mìíràn Kí ó tó lọ, ó pín iṣẹ́ fún àwọn tí ó gbà ṣíṣẹ́, àní, iṣẹ́ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ṣe nígbà tí ó bá lọ, ó ní kí ọ̀kan nínú wọn dúró lẹ́nu-ọ̀nà láti máa ṣọ́nà títí òun yóò fi dé Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin pẹ̀lú ní láti máa fi ìrètí sọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ àkókò tí baálé ilé yóò da Bóyá ní ìrọ̀lẹ́ ni o, tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru, tàbí nígbà tí àkùkọ máa ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀ Pé nígbà tí bá dé lójijì, kó má ṣe bá yín lójú oorun Ohun tí mo wí fún un yín, mo wí ì fuń gbogbo ènìyàn Ẹ máa ṣọ́nà!  A Da Tùràrí sí Ara Jésù Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ni Àjọ ìrékọjá àti àjọ tí wọ́n ń fi àkàrà àìwú se ku ọ̀túnla Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin sì ń wá ọ̀nà láti mú Jésù ní ìkọ̀kọ̀, kí wọn sì pa á Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, A kò ní mú un ní ọjọ́ Àjọ, kí àwọn ènìyàn má bá á fa ìjàngbọ̀n Nígbà tí ó sì wà ní Bẹ́tanì ni ilé Símónì adẹ́tẹ̀ bí ó ti jókòó ti oúnjẹ, obìnrin kan wọlé, ti òun ti ìgò òróró ìpara olówó iyebíye, ó sí ìgò náà, ó sì da òróró náà lé Jésù lórí Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́ Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò Òun ìbá tà á ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn talákà lọ́rẹ Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára Ṣùgbọ́n Jésù wí fún pé, Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé Nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi Nígbà gbogbo ni àwọn talákà wà ní àárin yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkugbà tí ẹ bá fẹ́ Ó ti ṣe èyí tí ó lè ṣe, Ó ti fi òróró kùn mí ni ara ní ìmúra sílẹ̀ de ìgbà tí wọn yóò sin òkú mi Lóótọ́ ni mo wí fún un yín, níbikíbi tí wọ́n bá ti wàásù mi, ní gbogbo ayé, wọn kò ní ṣe aláìsọ ohun tí obìnrin yìí ṣe pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀ Nígbà náà ni Júdásì Ìsíkáríọtù, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfàá, láti ṣètò bí yóò ti fi Jésù lé wọn lọ́wọ́ Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì pinnu láti fún un ní owó Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jésù lé wọn lọ́wọ́ Ní ọjọ́ kìnínní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù bi í léèrè pé, Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèṣè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àṣè ìrékọjá Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru iṣà omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baale náà pé, Olùkọ́ rán wa pé Ní bo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àṣè ìrékọja pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi Òun yóò sì mú un yín lọ sí gbàngàn ńlá kan lókè ilé náà, tí a ti ṣe lọ́sọ́ Níbẹ̀ ni kí ẹ pèṣè sílẹ̀ dè wá Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárin ìlú Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jésù tí sọ fún wọn Wọ́n sì pèsè àṣè ìrékọjá Nígbà tí ó di alẹ́, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé ṣíbẹ̀ Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jésù wí pé, Lóòtọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fí mí hàn Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọkọ̀ọ̀kan wí pé, Dájúdájú, kì í ṣe èmi Ó sì dáhùn wí pé, Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi jẹun nísinsin yìí ni Ní tòótọ́ Ọmọ-Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀ Ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ-Ènìyàn hàn Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá Bí wọ́n ti ń jẹun lọ́wọ́, Jésù mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn Ó wí pé Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi Ó sì tún gbé ago wáìnì, ó gbàdúrà ọpẹ́ sí Ọlọ́run Ó sì gbé e fún wọn Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀ Ó sì wí fún wọn pé, Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi ti májẹ̀mú túntún, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn Lóótọ̀ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní titun nínú ìjọba Ọlọ́run Lẹ́yìn náà wọ́n kọ orin, wọ́n sì gun orí òkè ólífì lọ Jésù sì wí fún wọn pé, Gbogbo yín ni ẹ ń bọ̀ wá kosẹ̀ lára mi ni oru òní, a ti kọ̀wé rẹ pé  Èmi yóò lu olùsọ́-àgùntàn àwọn agbo àgùntàn yóò sì fọ́nká Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà ti mo ba jíǹde tan, Èmi yóò ṣíwájú yin lọ sí Gálílì Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn, ó wí pé, Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ sá kúrò lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní sá Jésù wá wí fún un pé, Jẹ́ kí ń sọ òótọ́ fún ọ Kí àkùkọ tóó kọ lẹ́ẹ̀kejì ní òwúrọ̀ ọ̀la, ìwọ, pàápàá yóò ti sọ lẹ́ẹ̀mẹ̀ta wí pe ìwọ kò mọ̀ mí rí Ṣùgbọ́n Pétérù faraya, ó wí pé, Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́ rí Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe Nígbà tí wọ́n dé ibi kan tí wọ́n ń pè ní ọgbà Gétísémánì Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Ẹ jókòó dè mí níhìnín títí n ó fi lọ gbàdúrà Ó sì mú Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù lọ pẹ̀lú rẹ̀ Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi Ó sì wí fún wọn pé, Títí dé kú Ẹ dúró níhìnín kí ẹ sì máa mi sọ́nà Ó sì lọ ṣíwájú díẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá Ó sì wí pé, Á bà Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kìí ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò se èyí tí ìwọ fẹ́ Nígbà tí ó sì páda dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun Ó sì wí fún Pétérù pé, Símónì, o ń sùn ni Ìwọ kò lè bá mi sọ́nà fún wákàtí kan Ẹ máa sọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, ki ẹ má ba à bọ́ sínú ìdánwó Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, Ẹ̀mí ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara   Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ì bá fún un Ó sì wá nígbà kẹ́ta, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ máa sùn kí ẹ sì máa sinmi ó tó bẹ́ẹ, wákàtí náà ti dé, wò ó, a fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́ Ẹ dìde, Ẹ jẹ́ kí a máa lọ Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòòsí! Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, lójú ẹsẹ̀ náà ni Júdásì ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá dé pẹ̀lú Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti idà àti kùmọ́ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà, àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn àgbààgbà Júù ni ó rán wọn wa Júdásì tí fí àmì fún wọn wí pe, Ẹni tí mo bá fi ẹnu kò lẹ́nu nínú wọn, òun ní Jésù, Ẹ mú un Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, Júdásì lọ sì ọ̀dọ̀ rẹ̀ tààrá, ó wí pé, Rábì! ó sì fi ẹnu kò Jésù lẹ́nu Wọ́n sì mú Jésù Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró idà rẹ̀ yọ, ó fi sá ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ge etí rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ Nígbà náà Jésù dáhùn, ó bi wọ́n léèrè pé, Ṣé Èmi ni ẹ̀yin jáde tọ̀ wá bi olè, ti ẹ̀yin ti idà àti kùmọ̀ láti mú Ojoojúmọ́ ni èmi wà pẹ̀lú yín ní tẹ́ḿpìlì, tí mo ń kọ́ni ẹ kò mú mi Ṣùgbọ́n eléyìí ṣẹlẹ̀, kí ohun tí ìwé Mímọ́ wí lè ṣẹ Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti fi í sílẹ̀, wọ́n sá lọ Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ bo ìhòòhò rẹ̀ àwọn ọmọ-ogun gbìyànjú láti mú òun náà Ó sì fi aṣọ funfun náà sílẹ̀ fún wọn, ó sì sá lọ ní ìhòòhò Wọ́n mú Jésù lọ sí ilé olórí àlùfáà, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù àti àwọn olùkọ́-òfin wọn péjọ síbẹ̀ Pétérù tẹ̀lé Jésù lókèèrè, ó sì yọ́ wọ inú àgbàlá olórí àlùfáà, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ó ń yáná Bí ó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ń wá ẹni tí yóò jẹ́rí èkè sí Jésù, èyí tí ó jọjú dáadáa láti lè dájọ́ ikú fún un Ṣùgbọ́n wọn kò rí Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí wọ̀n ní kò bá ara wọn mu Níkẹyìn àwọn kan dìde, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ní A gbọ́ tí ó wí pé Èmi yóò wó tẹ́ḿpìlì tí ẹ fi ọwọ́ kọ́ yìí, nígbà tí yóò bá sì fi di ọjọ́ kẹta, èmi yóò kọ́ òmíràn ti a kò fi ọwọ́ ènìyàn kọ́   Ṣíbẹ̀, ẹ̀rí i wọn kò dọ́gba Nígbà náà ni àlùfáà àgbà dìde, ó bọ́ ṣíwájú Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi Jésù léèrè, ó ní, Ṣé o kò ní fèsì sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi sùn ọ Kí ni ìwọ gan an ní sọ fúnrarẹ Ṣùgbọ́n Jésù dákẹ́ Olórí àlùfáà tún bi í, lẹ́ẹ̀kan sí i, ò ní, Ṣé ìwọ ni Kírísítì náà, Ọmọ Ọlọ́run Jésù wá dáhùn, ó ni, Èmi ni Ẹ̀yin yóò sì rí Ọmọ-Ènìyàn tí yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ẹ̀yin yóò sì tún rí Ọmọ-Ènìyàn tí ó ń bọ̀ láti inú àwọ̀sánmọ̀ ojú ọ̀run Nígbà náà ni Olórí àlùfáà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, Kí ló kù tì a ń wá Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rí fún Ẹ̀yin fúnra yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì tí ó sọ Kí ni ẹ rò pé ó tọ́ kí a ṣe Gbogbo wọ́n sì dáhùn wí pé, Ó jẹ̀bi ìkú Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ̀ sí i lára Wọ́n dì í lójú Wọ́n ń gbà a lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, Sọtẹ́lẹ̀! Àwọn olùsọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú Ní àkókò yìí Pétérù wà ní ìṣàlẹ́ inú àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́ Nínú àgbàlá yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin àlùfáà àgbà kíyèsí í tí Pétérù ń yáná Nigba tí ó rí Pétérù tí ó ti yáná, Ó tẹjú mọ́ ọn, ó sì sọ gbangba pé, Ìwọ pàápàá wà pẹ̀lú Jésù ara Násárẹ̀tì Ṣùgbọ́n Pétérú ṣẹ́, ó ni, N kò mọ Jésù náà rí ohun tí ó ń sọ yìí kò tilẹ̀ yé mi Pétérù sì jáde lọ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́ Àkùkọ sì kọ Ọmọbìnrin yẹn sì tún rí Pétérù Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ Ó ní, Ọkùnrin yìí gan an jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù Ṣùgbọ́n Pétérù tún ṣẹ́ Nígbà tí ó sí tún ṣẹ díẹ̀ sí i, àwọn tí wọ́n dúró lẹ́gbẹ́ Pétérù wá wí fún un pé, Láìṣe àní àní, ara wọn ni ìwọ Nítorí ará Gálílì ni ìwọ náà Nígbà náà ni Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́ ó sì ń búra, ó ni, N kò mọ ẹni ti ẹ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí rí! Lójú kan náà tí àkùkọ yìí kọ lẹ́ẹ̀kejì Pétérù rántí ọ̀rọ̀ Jésù fún un pé, Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, ìwọ yóò ṣẹ́ mí nígbà mẹ́ta Ó sì rẹ̀ ẹ́ láti inú ọkàn wá, ó sì sọkùn Jésù Jẹ́jọ́ Níwájú Pílátù Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, àwọn olórí àlùfáà, àwọn àgbààgbà, àwọn alùkọ́ òfin àti gbogbo àjọ ìgbìmọ̀ fi ẹnu kò lórí ohun tí wọn yóò ṣe Wọ́n sì de Jésù, wọ́n mú un lọ, wọ́n sì fi lé Pílátù lọ́wọ́ Pílátù sì bi í léèrè, ó ni, Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù Jésù sì dáhùn pé, Ìwọ wí Àwọn olórí àlùfáà fi ẹ̀sùn ohun púpọ̀ kàn án Pílátù sì tún bi í léèrè pé, Ṣe ìwọ kò dáhùn ni Wo gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ Ṣùgbọ́n Jésù kò da lohùn síbẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ ti ẹnu fi ya Pílátù Ní báyìí, nígbà àjọ, gẹ́gẹ́ bí àsà, òun a máa dá òǹdè kan sílẹ̀ fún àwọn, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá béèrè fún Ọkùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bárábà Wọ́n ti ju òun àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, nítorí wọ́n sọ̀tẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì pa ènìyàn nínú ìdìtẹ̀ wọn Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì lọ bá Pílátù, wọ́n ní kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn ní ọdọọdún Pílátù béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, Ṣe ẹ̀yín ń fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yin òun mọ̀ pé nítorí ìlara ni àwọn olórí àlùfáà ṣe fà Jésù lé òun lọ́wọ́ Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà ru ọ̀pọ̀ ènìyàn sókè pé, kí ó kúkú dá Bárábà dá sílẹ̀ fún wọn Pílátù sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Kí ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe pẹ̀lú ẹni ti ẹ̀yin n pè ní ọba àwọn Júù Wọ́n sì tún kígbe sókè pé, Kàn án mọ àgbélébùú! Nígbà náà ni Pílátù bi wọn léèrè pé, Èéṣe Búburú kí ni ó ṣe Wọ́n sì kígbe sókè gidigidi wí pé, Kàn án mọ́ àgbélébùú! Pilatù sì ń fẹ́ se èyí tí ó wu àwọn ènìyàn, ó dá Bárábà sílẹ̀ fún wọn Nígbà tí ó sì na Jésù tan o fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn an mọ́ àgbélébùú Àwọn ọmọ-ogun sì fà á jáde lọ sínú gbangba , wọ́n sì pe gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun jọ Wọn sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ̀ ọ́, wọ́n hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i kí ì, wí pé Kábíyèsí, Ọba àwọn Júù Wọ́n sì fi ọ̀pá ìyè lù ú lórí, wọ́n sì tutọ́ síi lára, wọ́n sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un Nígbà tí wọ́n sì fi ṣẹ̀sín tan, wọ́n sì bọ aṣọ elésè àlùkò náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì mú un jáde lọ láti kàn án mọ́ àgbélébùú Wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń kọjá lọ Símónì ni orúkọ rẹ̀ Ará Kírénì ni Òun ni baba Alekisáńdérù àti Rúfọ́ọ̀sì Wọ́n sì mú un nípá, pé kí ó rú àgbélébùú Jésù Wọ́n sì mú Jésù wá sí Gọ́lgọ́tà, Wọ́n sì fi wáìnì tí a dàpọ̀ mọ́ òjìá fún un mu, ṣùgbọ́n òun kò gbà á Wọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn báà lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú Àkọlé Ìfisùn tí wọ́n kọ sókè orí rẹ̀ ni ỌBA ÀWỌN JÚÙ Wọ́n sì kan àwọn olè méjì mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, èkejì lọ́wọ́ òsì rẹ̀ Eléyìí mú àṣọtẹ́lẹ̀ ìwé Mímọ́ ṣẹ wí pé, Wọ́n kà á pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń mi orí wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ké pé, Áà! Ìwọ tí yóò wó tẹ́ḿpìlì tí yóò sì tún un kọ́ láàrin ọjọ́ mẹ́ta Tí ó bá lágbára tó bẹ́ẹ̀, gba ara rẹ là, kí o sì ti orí àgbélébùú sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í sẹ̀sín láàrin ara wọn, wọ́n wí pé, Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà Jẹ́ kí Kírísítì, Ọba Ísírẹ̀lì, sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélèbùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́ Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀ Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsàn-án Ní wákàtí kẹsàn-án ni Jésù kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, ÈLÓÍ, ÈLÓÍ, LÀMÁ SÀBÁKÍTANÍ ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀ Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, Wò ó ó ń pe Èlíjà Nígbà náà ni ẹnìkan wá sáré lọ ki kàn-ìn-kàn-ìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi lé orí ọ̀pá, ó sì nà án sí Jésù kí ó lè mu ún Ó wí pé, Ẹ jẹ́ kí a máa wò ó, bóyá Èlíjà yóò wá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ Jésù sì tún kígbe soke ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ Aṣọ ìkélé tẹ́ḿpìlì sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀ Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jésù rí i tí kígbe sókè báyìí tí ó sì èémí ìgbẹ̀yìn, ó wí pé, Dájúdájú Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í se Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń najú wò ó láti òkèèrè Màríà Magidalénì wà lára àwọn obìnrin náà, àti Màríà ìyá Jákọ́bù kékeré àti ti Jósè àti, Ṣálómè Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Gálílì máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìranṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerúsálémù Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà sì ṣú, Jóṣẹ́fù ará Arimatíyà wá, ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ẹni tí ń retí ìjọba Ọlọ́run, ó fi ìgboyà lọ sí iwájú Pílátù láti tọrọ òkú Jésù Ẹnú ya Pílátù láti gbọ́ pé Jésù ti kú Nítorí náà ó pe balógun-ọ̀rún, ó sì bí i léèrè bóyá Jésù ti kú ní tòótọ́ Nígbà tí balógun-ọ̀rún náà sì fún Pílátù ni ìdánilójú pé Jésù ti kú, Pílátù yọ̀ǹda òkú rẹ̀ fún Jóṣẹ́fù Jóṣẹ́fù sì ti ra aṣọ ọ̀gbọ̀ wá Ó sọ òkú Jésù kalẹ̀ ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ náà dì í Ó sì tẹ́ ẹ sí inú ibojì, tí wọ́n gbẹ́ sí ara àpáta Ó wá yí òkúta dí ẹnu ibojì náà Màríà Magidalénì àti Màríà ìyá Jósè ń wò ó bi Jóṣẹ́fù ti n tẹ́ Jésù sí ibojì Àjíǹde Nígbà tí ọjọ́ ìsinmi sì kọjá, Màríà Magidalénì àti Sálómì àti Màríà ìyá Jákọ́bù àti Sálómè mú òróro olóòórùn dídùn wá kí wọn bá à le fi kun Jésù lára Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sè, wọ́n wá sí ibi ibojì nigbà tí òòrùn bẹ̀rẹ̀ sí yọ, wọn sì ń bi ara wọn léèrè pé, Ta ni yóò yí òkúta náà kúrò lẹ́nu ibojì fún wa Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn sì wò ó, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta tí ó tóbi gidigidi náà kúrò Nígbà tí wọ́n sì wọ inú ibojì náà, wọ́n rí ọ̀dọ́mọkùnrin kàn tí ó wọ aṣọ funfun, ó jókòó ní apá ọ̀tún, ẹnú sì yà wọn Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ má bẹ̀rù Ẹ̀yin ń wá Jésì tí Násárẹ́tì, tí a kàn mọ́ àgbélébùú Ó jíǹde! Kò sí níhìnín yìí mọ́, Ẹ wo ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí Ṣùgbọ́n ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ títí kan Pétérù wí pé, Òun ti ń lọ ṣíwájú yín sí Gálílì Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín   Wọ́n sá jáde lọ kánkán, wọn sì sáré kúrò ní ibi ibojì náà, nítorí tí wọ́n wárìrì ẹ̀rù sì bà wọn gidigidi wọn kò wí ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù bá wọ́n Nìgbà tí Jésù jíǹde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sè, ó kọ́ fi ara hàn fun Màríà Magidalénì, ni ara ẹni tí ó ti lé ẹ̀mi Èsù méje jáde Òun sì lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá a gbé, bí wọn ti ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń sọkún Àti àwọn, nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ó ti di alààyè, àti pé, òun ti rí i, wọn kò gbàgbọ́ Lẹ́yìn èyí, ó sì fi ara hàn fún àwọn méjì ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn ní ọ̀nà, tí wọ́n sì ń lọ sí ìgbéríko Nígbà tí wọ́n sì mọ ẹni tí i ṣe, wọ́n sì lọ ròyìn fún àwọn ìyókù, ṣíbẹ̀, àwọn ìyókù kò gbà wọ́n gbọ́ Lẹ́yìn náà, Jésù fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn mọ́kànlá níbi tí wọ́n ti jìjọ ń jẹun Ó sì bá wọn wí fún àìgbàgbọ́ àti ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba ẹ̀rí àwọn tí ó ti rí i lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ gbọ́ Ó sì wí fún wọn pé, Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì máa wàásù ìyìn rere mi fún gbogbo ẹ̀dá Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí a sì tẹ̀bọmi yóò là Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò gbàgbọ́ yóò jẹ̀bi Àmì wọ̀nyí yóò sì máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ Ní orúkọ mi ni wọ́n yóò máa lé ẹ̀mí èsù jáde Wọn yóò máa fi èdè titun sọ̀rọ̀ Wọn yóò sì gbé ejò lọ́wọ́, bí wọ́n bá sì jẹ májèlé kò ní pa wọ́n lára rárá Wọ́n yóò gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóò sì dá Nígbà tí Jésù Olúwa sì ti bá wọn sọ̀rọ̀ báyìí tan, á gbé e lọ sí ọ̀run, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì jáde lọ Wọ́n ń wàásù káàkiri Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, ó sì ń fi ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nípa àwọn àmì tí ó tẹ̀lé e Jésù Wo Aláàrùn Ẹ̀gbà sàn Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, nígbà tí Jésù tún padà wọ Kápánámù, òkìkì kàn pé ó ti wà nínú ilé Láìpẹ́, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti kún ilé tí ó dé sí tó bẹ́ẹ̀ tí inú ilé àti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ní ìta kò gba ẹyọ ẹnìkan mọ́, ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà sí wọn Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jésù, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jésù wà Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ẹní rẹ̀ níwájú Jésù Nígbà tí Jésù sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́ Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé, È é ṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí O ń sọ̀rọ̀ òdì Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan Lojú kan náà bí Jésù tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, È é ṣe tí ẹ̀yìn fí ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín Èwo ni ó rọrùn jù láti wí fún arọ náà pé A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ, tàbí wí pé, Dìde sì gbé àkéte rẹ, ki o si máa rin Ṣùgbọ́n ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Ènìyàn ní agbára ní ayé làti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ji ní Ó wí fún ọkùnrin arọ náà pé, Mo wí fún ọ, dìde, gbé ẹní rẹ kí ó sì máa lọ ilé rẹ Lójúkan-náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀ Ó gbé ẹní rẹ̀ Ó sì jáde lọ lojú gbogbo wọn Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, Àwa kò rí irú èyí rí! Nígbà náà, Jésù tún jáde lọ sí etí òkun Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ wọn Bí ó ti ń rin etí òkun lọ sókè, ó rí Léfì ọmọ Álíféù tí ó jókòó nínú àgọ́ níbi tí ó ti ń gba owó orí, Jésù sì wí fún un pé, Tẹ̀ lé mi, Léfì dìde, ó sì ń tẹ̀lé e Ó si ṣe, bí ó sì ti jókòó tí oúnjẹ ni ilé Léfì, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jésù jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí ti wọn pọ̀ ti wọn tẹ̀lé e Nígbà tí àwọn olùkọ òfin àti àwọn Farisí rí ì tí ó ń bá àwọn agbowó-òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, wọn wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, È é ti rí tí ó fi ń bá àwọn agbowó-òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun Nígbà tí Jésù gbọ́, ó sọ fún wọn wí pé, Àwọn tí ara wọ́n dá kò wa oníṣègùn, bí ko ṣe àwọn tí ara wọn kò dá Èmi kò wá lati sọ fún àwọn ènìyàn rere láti ronúpìwàdà, bí kò ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn Farisí a máa gbààwẹ̀ Àwọn ènìyàn kan sì wá, wọ́n sì bi í pé, È é ṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Farisí fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ kò gbààwẹ̀ Jésù dáhùn wí pé, Báwo ni àwọn àlejò ọkọ ìyàwó yóò se máa gbàwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó sì wà lọ́dọ̀ wọn Ṣùgbọ́n láìpẹ́ ọjọ́, a ó gba ọkọ ìyàwọ kúrò lọ́dọ̀ wọn Nígbà náà wọn yóò gbààwẹ̀ ni ọjọ́ wọ̀nyí Kò si ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ túntún lẹ ògbólógbo ẹ̀wù, bí ó ba se bẹ́ẹ̀, èyí túntún ti a fi lẹ̀ ẹ́ yóò fà ya kúrò lára ògbólógbòó, yíyọ́ rẹ̀ yóò sí burú púpọ̀ jù Kò sì sí ẹni tí ń fi ọtí wáìnì túntún sínú ìgò wáìni ògbólógbó Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí wáìnì náà yóò fa ìgò náà ya, ọtí wáìnì a si dàànu, bákan náà ni ìgò náà, ṣùgbọ́n ọtí wáìnì tuntun ni a n fi sínú ìgò wáìnì tuntun Ó sì ṣe ni ọjọ ìsinmi, bí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń kọjá lọ láàrin oko ọkà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya ìpẹ́ ọká Díẹ̀ nínú àwọn Farisí wí fún Jésù pé, Wò ó, è é ṣe ti wọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi Ó dá wọn lóhùn pé, Ẹ̀yín kò tí kà ohun tí Dáfídì ṣe, nígbà tí ó ṣe aláìní, tí ebi sì ń pa á, òun àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ Bí ó tí wọ ilé Ọlọ́run lọ ni ọjọ́ Ábíátarì olórí àlùfáà, tí ó sì jẹ búrẹ́dì ìfihàn ti kò tọ́ fún un láti jẹ bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà, ó sì tún fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ Ó sì wí fún wọ́n pé, a dá ọjọ́ ìsinmi fún ènìyàn, Ṣùgbọ́n a kò dá ènìyàn fún ọjọ ìsinmi Nítorí náà Ọmọ Ènìyàn ni Olúwa ọjọ́ ìsinmi pẹ̀lú Ọ̀pọ̀ Ènìyàn Tẹ̀lé Jésù Nígbà tí Jésù wá sí sínágọ́gù Sì kíyèsí i ọkùnrin kan wà níbẹ̀, tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ Àwọ́n kan nínú wọn sì ń wa ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jésù, ítorí náà, wọn ń sọ Ọ́ bí yóò u un láradá ní ọjọ́ ìsinmi Jésù wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé, Dìde dúró ní iwájú ìjọ ènìyàn Nígbà náà ni Jésù bèèrè lọ́wọ́ wọ́n pé, Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, Na ọwọ́ rẹ jáde Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá Lójúkan-náà, àwọn Farisí jáde lọ, láti bá àwọn ọmọ ẹ̀yin Hẹ́rọ́dù gbìmọ̀ pọ̀, bí wọn yóò ṣe pa Jésù Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí òkun Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Gálílì àti Jùdíà sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrpyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Jùdíà, Jerúsálémù àti Ìdúmíà, àti láti apákejì odò Jọ́dání àti láti ihà Tírè àti Ṣídónì Nítorí ẹ̀rọ̀, Jésù sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ lati sètò ọkọ̀ ojú omi kekere kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn ẹ̀rọ̀ sẹ́yìn Nítorí tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá lọ́jọ́ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìsàn ló yí i ká, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti fi ọwọ́ kàn án Ìgbàkúùgbà tí àwọn tí ó kún fún ẹ̀mí àìmọ́ bá ti fojú gán-án ní rẹ̀, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀ Wọn a sì kígbe lóhùn-rara wí pé, Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí wọn má ṣe fi òun hàn Jésù gun orí òkè lọ ó gun orí òkè lọ, ó sì pe àwọn kan tí ó yàn láti wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá Ó yan àwọn méjìlá-ó pè wọ́n ní apostẹli-kí wọ́n kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí wọn kí ó lè lọ láti wàásù àti láti lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí Èsù jáde Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn, Ṣímóní Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ Àti Ańdérù, Fílípì, Bátólómíù, Mátíù, Tómásì, Jákọ́bù , Tádéù, Símónì Àti Júdásì Ísíkáríọ́tù, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn Nígbà náà ni Jésù sì wọ inú ilé kan, àwọn ẹ̀rọ̀sì tún kórájọ, tó bẹ́ẹ̀ tí Òun àti àwọn Ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ kò rí ààyè láti jẹun Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wá láti mu un lọ ilé, nítorí tí wọn wí pé, Orí rẹ̀ ti dàrú Àwọn olùkọ́ni-ni-òfin ṣọkàlẹ̀ wá láti Jérúsálẹ́mù, wọn sì wí pé, Ó ni Béélísébúbù, olórí àwọn ẹ̀mí Èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde! Jésù pè wọ́n, ó sì fi òwé bá wọn sọ̀rọ̀ Báwo ni Èsù ṣe lè lé èsù jáde Bí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjọba náà yóò wó lulẹ̀ Bákan náà, bí ilé kan bá sì yapa sí ara rẹ, ilé náà kí yóò leè dúró Bí Èṣù bá sì díde sí ara rẹ, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé Kò sí ẹni tí ó le wọ ilé ọkùnrin alágbára kan lọ, kí ó sì kó o ní erù lọ, bí kò se pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà ní okùn, nígbà náà ni yóò lè kó ẹrù ní ilé rẹ̀ Lóòótọ́ ní mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a ó dárí jin àwọn ọmọ ènìyàn, àti gbogbo ọ̀rọ̀ òdì Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, kì yóò rí ìdáríjì títí ayé, ṣùgbọ́n ó wà nínú èwù ẹ̀bi àìnípẹ̀kun Òun sọ eléyìí fún wọn, nítorí tí wọ́n sọ pé, Nípa agbára ẹ̀mí Èṣù ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ̀ dé Wọ́n dúró lóde, wọ́n sì rán ẹnìkan sí i pé kí ó pè é wá Àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wí fún un pé, Ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ wà lóde Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn wí pé, Ta ni í ṣe ìyá mi tàbí àwọn arákùnrin mi Ó sì wò gbogbo àwọn tí ó jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ yíká, ó sì wí pé, Àwọn wọ̀nyí ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi Òwe Afúnrúgbìn Jésù sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ní létí òkun Àwọn ijọ̀ ènìyàn tí ó yí i ká pọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú-omi, tí ó sì jókòó nínú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun, nígbà tí àwọn ènìyàn sì wà ní ilẹ̀ létí òkun Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀ Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpátá, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀ Láìpẹ́ ọjọ́, ó hú jáde Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jónà, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrin ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbà sókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúngbìn náà kò le so èso Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Ó sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún Jésù sì wí pé, Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́ Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léérèè wí pé, Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀ Ó sì dá wọn lóhùn pé, Ẹ̀yin ni a gbà láàyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà Bí ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé,  wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!  Ṣùgbọ́n Jésù wí fún wọn pé, Bí òwe tí ó rọrùn yìí kò bá yé e yín Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn mìíràn tí mo ń sọ fún un yín Afúrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà Àwọn èṣo tó bọ́ sí ojú ọ̀nà líle, ni àwọn ọlọ́kan líle tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lójúkan náà èṣù wá ó sì mú kí wọn gbàgbé ohun tí wọ́n ti gbọ́ Bákan náà, àwọn tí ó bọ́ sórí àpata, ni àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣùgbọ́n kò ni gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀ ní ọkàn wọn Ṣùgbọ́n wọn a wà fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà nígbà ti wàhálà tàbí inúnibínu bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà, wọn a kọsẹ̀ Àwọn tí ó bọ́ sáàrin ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì gbà á lótìítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run, ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùnún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn Ó si wí fún wọn pé, A ha lè gbé fìtílà wá láti fí sábẹ́ òsùwọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte Rárá o, kí á máa sì se gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsinyìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkòkọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́ Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, Ẹ maá kíyèsí ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òsùnwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ̀n náà ni a ó fi wọ̀n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a ó tún fi fún síi àti lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ń, ni a ó ti gba èyí náà tí ó ní Ó sì tún ọ èyí pé, Èyí ni a lè fí ìjọba Ọlọ́run wé Ọkùnrin kan ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀ Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìdè, irúgbìn náà hù jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀ Nítorí tí ilẹ̀ kọ́kọ́ hù èso jáde fún ara rẹ̀, ó mú èéhù ewé jáde, èyí tí ó tẹ̀lé e ni orí ọkà, ní ìparí, ọkà náà gbó Nígbà tí èṣo bá gbó tan, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòje bọ inú ọkà náà, ó sì kórè rẹ̀ Jésù sì tún wí pé, Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀ Ó dàbí èso hóró Músítádì kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan níńu àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbin sínú ilẹ̀ Ṣíbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbà sókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgba yókù lọ Ó sì ya ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbò-bò Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó Kìkì òwe ni Jésù fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìta gbangba rẹ̀ Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó bá sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, òun a sì sọ ìtumọ̀ ohun gbogbo Nígbà tí alẹ́ lẹ́, Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Ẹ jẹ́ kí a rékọjá sí apákejì Nígbà tí wọn ti tú ìjọ ká, wọ́n si gbà á sínú ọkọ̀ ojú omi gẹ́gẹ́ bí ó ti wà Àwọn ọkọ̀ ojú-omi kékeré mìíràn sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ Ìji líle ńlá kan sì dìde, omi sì ń bù sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ síi kún fún omi, ó sì fẹ́rẹ rì Jésù ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí Wọ́n sì jí i lóhùn rara wí pé, Olùkọ́ni, tàbí ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ rì Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà Lẹ́yìn náà, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Èése tí ẹ̀yin fi ń ṣojo bẹ́ẹ̀ Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ì ní ìgbàgbọ́ ṣíbẹ̀síbẹ̀ Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, Irú ọkùnrin wo ni èyí, tí ìjì àti òkun ń gbọ́ tirẹ̀! Ìwòsàn ọkùnrin ẹlẹ́mìí Èṣù Wọn lọ si apákejì adágún ní ẹba ilẹ̀ àwọn ará Gádárà Bí Jésù sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀ Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ìbojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọn ti ń fi ṣẹ́kẹ́sẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹṣẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹṣẹ rẹ Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀ Tọ̀sán-tòru láàrin àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀ Nígbà tí ó sì rí Jésù látòkèrè, ó sí sáré lọ láti pàdé rẹ̀ Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, Kí ni ṣe tèmi tìrẹ, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀ga Ògo Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró Nítorí tí Ó wí fún un pé, Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́! Jésù sì bi í léèrè pé, Kí ni orúkọ rẹ Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì dáhùn wí pé, Líjíọ́nì, nítorí àwa pọ̀ Nígbà náà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jésù gidigidi, kí ó má ṣe rán àwọn jáde kúrò ní agbègbè náà Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan sì ń jẹ lẹ́bàá òké Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ Jésù pé, Rán wa lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọnni kí awa le è wọ inú wọn lọ Jésù fún wọn láàyè, àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà lọ Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà tí ó tó ìwọ̀n ẹgbàá sì túká lọ́gán, wọ́n sì sáré lọ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè rọ́ sínú òkun, wọ́n sì ṣègbé Àwọn olùtọ́jú ẹran wọ̀nyí sì sá lọ sí àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèkéé, wọ́n sì ń tan ìròyìn náà ká bí wọ́n ti ń sáré Àwọn ènìyàn sì tú jáde láti fojú gán-án-ní ohun náà tí ó sẹlẹ̀ Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí-èṣù, tí ó jokòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ iye rẹ sì bọ̀ sípọ, ẹ̀rù sì bà wọ́n Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó sẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mí àìmọ́, wọn si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú Nígbà náà, àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ Jésù pé kí ó fi agbégbé àwọn sílẹ̀ Bí Jésù ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú-omi lọ, ọkùnrin náà tí ó ti ní ẹ̀mí àìmọ́ tẹ̀lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ pé kí òun lè bá a lọ Jésù kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, Lọ sí ilé sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sì sọ fún wọn bí Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún ọ, àti bí ó sì ti ṣàánú fún ọ Nítorí naà, ọkùnrin yìí padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ní Dekapolisi nípa ohun ńlá tí Jésù ṣe fún un Ẹnu sì ya gbogbo ènìyàn Nígbà tí Jésù sì ti inú ọkọ̀ rékọjá sí apá kejì òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ yí i ká ní etí òkun Ọ̀kan nínú àwọn olórí sínágọ́gù tí à ń pè ni Jáírù wá sọ́dọ̀ Jésù, nígbà tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀ Ó sì bẹ̀ ẹ́ gidigidi pé, Ọmọbìnrin mi wà lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, wá fi ọwọ́ rẹ lé e, kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè Jésù sì ń bá a lọ Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn Obìnrin kan sì wà láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i Nígbà tí ó sì gburo iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀ Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, Bí mo bá ṣá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ sì gbẹ lẹṣẹkẹṣẹ, òun sì mọ̀ lára rẹ̀ pé, a mú òun láradá kúrò nínú àrùn náà Lọ́gán, Jésù sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé agbára jáde lára òun Ó yípadà láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì béèrè, Ta ni ó fi ọwọ́ kan aṣọ mi Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, Ìwọ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó rọ̀gbà yí ọ ká, ìwọ́ sì tún ń bèèrè ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn ọ́ Ṣíbẹ̀, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí wò yíká láti rí ẹni náà, tí ó fi ọwọ́ kan òun Nígbà náà, obìnrin náà kún fún ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nítorí ó ti mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun Ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ ohun tí òun ti ṣe Jésù sì wí fún un pé, Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dá Má a lọ ní àlàáfíà, ìwọ sì ti sàn nínú àrùn rẹ Bí Jésù sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jáírù olorí sínágọ́gù wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jésù lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù Ṣùgbọ́n bi Jésù ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jáírù pé, Má bẹ̀rù, sá à gbà mí gbọ́ nìkan Nígbà náà, Jésù dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jáírù, bí kò ṣe Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jésù rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún Ó wọ inú ilé lọ, Ó sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohunréré ẹkún Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni Wọ́n sì fi í rẹ́rín Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ mẹ́ta Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí Ó gba a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, Tàlítà kúùmì Lẹ́sẹ̀kan-náà, ọmọbìnrin náà sì dìde Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì ba wọn, ẹnú sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi Jésù sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ Wòlíì Tí Kò Ní Ọlá Jésù fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ìlú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí sínágọ́gù láti kọ́ àwọn ènìyàn ẹnu sì yà àwọn ènìyàn púpọ̀ tí ó gbọ́, wọ́n wí pé, Níbo ni ọkùnrin yìí gbé ti rí nǹkan wọ̀nyí Irú ọgbọ́n kí ni èyí tí a fi fún un, ti irú iṣẹ́ ìyanu báyìí ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe À bí kì í ṣe kápẹ́ríta ni Àbí kì í ṣe ọmọ Màríà àti arákùnrin Jákọ́bù àti Jósẹ́fù, Júdásì àti Símónì Àbí kì í ṣe ẹni ti àwọn arábìnrin rẹ̀ ń gbé àárin wa níhìn ín Wọ́n sì kọsẹ̀ lára rẹ̀ Nígbà náà, Jésù wí fún wọn pé, A máa ń bu ọlá fún wòlíì níbi gbogbo àfi ní ìlú ara rẹ̀ àti láàrin àwọn ìdílé àti àwọn ẹbí òun pàápàá Nítorí àìgbàgbọ́ wọn, òun kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá láàrin wọn, àfi àwọn aláìsàn díẹ̀ tí ó gbé ọwọ́ lé lórí, tí wọ́n sì rí ìwòsàn Ẹnu si yà á nítorí àìgbàgbọ́ wọn Lẹ́yìn náà, Jésù lọ sí àárin àwọn ìletò kéékèèkéé, ó sì ń kọ́ wọn Ó sì pe àwọn méjìlá náà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí rán wọn lọ ní méjì-méjì, Ó sì fi àṣẹ fún wọn lórí ẹ̀mí àìmọ́ Òun sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ mú ohunkóhun lọ́wọ́, àfi ọ̀pá ìtilẹ̀ wọn Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, àpò, tàbí owó lọ́wọ́ Wọn kò tilẹ̀ gbodọ̀ mú ìpàrọ̀ bàtà tàbí aṣọ lọ́wọ́ Jésù wí pé, Ẹ dúró sí ilé kan ní ìletò kan Ẹ má ṣe ṣípò padà láti ilé dé ilé, nígbà tí ẹ bá wà ní ìlú náà Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tí kò sì gbọ́rọ̀ yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn-eruku ẹṣẹ̀ yín síbẹ̀ fún ẹ̀rí fún wọn Wọ́n jáde lọ láti wàásù ìrònúpìwàdà fún àwọn ènìyàn Wọ́n lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde Wọ́n sì ń fi òróró kun orí àwọn tí ara wọn kò dá, wọ́n sì mú wọn láradá Láìpẹ́, ọba Hẹ́rọ́dù gbọ́ nípa Jésù, nítorí níbi gbogbo ni a ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ Ọba náà rò pé, Jòhánù Onítẹ́bọ́mì jínde kúrò nínú òkú, nítorí náà ni iṣẹ́ ìyanu ṣe ń ṣe láti ọwọ́ rẹ Àwọn mìíràn wí pé, Èlíjà ní Àwọn mìíràn wí pé, Wòlíì bí ọ̀kan lára àwọn àtijọ́ tó ti kú ló tún padà sáyé Ṣùgbọ́n nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́ èyí, ó wí pé Jòhánù tí mo tí bẹ́ lórí ni ó ti jíǹde kúrò nínú òkú Hẹ́rọ́dù tikararẹ́ sá ti ránṣẹ mú Johanu, tìkaararẹ̀ sínu túbú nítorí Hẹrodíà aya Fílípì arákùnrin rẹ̀ nítorí tí ó fi ṣe aya Nítorí tí ó tẹnumọ́ ọn wí pé, Kò tọ́ sí ọ láti fi ìyàwó arákùnrin rẹ ṣe aya Nítorí náà ni Hẹ́rọ́díà ṣe ní ìn sínú, òun sì fẹ́ pa á, ṣùgbọ́n kò le se é Nítorí Hẹ́rọ́dù bẹ́rù Jòhánù, ó sì mọ̀ ọ́n ni olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni mímọ́, ó sì ń tọ́jú rẹ̀ Nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́rọ̀ Jóhànù, ó ṣe ohun púpọ̀, ó sì fi olórí ní Gálílì Níkẹ̀yìn Hẹ́rọ́díà rí ààyè Àkókò yìí ni ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù, òun sì pèṣè àsè ní ààfin ọba fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ àwọn balógun àti àwọn jàǹkànjànkàn ní Gálílì Nígbà náà, ni ọmọbìnrin Hẹ́rọ́díà wọlé tí ó jó Inú Hẹ́rọ́dù àti àwọn àlèjò rẹ̀ dùn tóbẹ́ẹ̀ tí ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé, Béèrè ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fi fún ọ Ó sì búra fún un wí pé, Ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́, ìbá à ṣe ìdajì ìjọba mi ni, èmi yóò fi fún ọ Ó jáde lọ sọ fún ìyá rẹ̀ pé Kí ní kí ń béèrè Ó dáhùn pé, Orí Jòhánù Onítẹ̀bọmi Ọmọbìnrin yìí sáré padà wá sọ́dọ̀ Hẹ̀rọ́dù ọba Ó sì wí fún un pé, Mo ń fẹ́ orí Jòhánù Onítẹ̀bọmi nísinsin-yìí nínú àwopọ̀kọ́ Inú ọba sì bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ, àti nítorí tí ó bá a jókòó pọ̀, kò sì fẹ́ kọ̀ fún un Nítorí èyí, ọba rán ẹ̀sọ ọ̀kan ó fi àṣẹ fún un pé, kí ó gbé orí Jòhánù wá Ọkùnrin náà sì lọ, ó bẹ́ Jòhánù lórí nínú túbú Ó sì gbé orí Jòhánù sí wa nínú àwopọ̀kọ́ Ó sì gbé e fún ọmọbìnrin náà Òun sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sì lọ tẹ́ ẹ sínú ibojì Àwọn àpósítélì ko ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n sí ròyìn ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe àti ohun gbogbo tí wọ́n ti kọ́ni Nígbà tí Jésù rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ ti wọ́n sì ń bọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí ààyè fún wọn láti jẹun, ó si wí fún wọn pé, Ẹ jẹ́ kí a kúrò láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí fún ìgbà díẹ̀, kí a sì sinmi Nítorí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tí ó parọ́rọ́ Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn ni o rí wọn nígbà tí wọ́n ń lọ Àwọn wọ̀nyí sì tí ó wá láti ìlú ńlá gbogbo sáré gba etí òkun, wọ́n sì ṣe déédé wọ́n bí wọ́n ti gúnlẹ̀ ní èbúté Bí Jésù ti ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, ó bá ọ̀pọ̀ ènìyàn bí i tí àtẹ̀yìnwá, tí wọ́n ti ń dúró dè e Ó káàánú fún wọn, nítorí wọ́n dàbí àgùntàn tí kò ní olùtọ́jú Ó sì kọ́ wọn ni ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀ Nígbà tí ọjọ́ sì ti bu lọ tán, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ ọ́ wa, wọ́n wí fún un pé, ibi aṣálẹ̀ ni ìbí yìí, ọjọ́ sì bù lọ tán Rán àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti lọ sí àwọn abúlé àti ìlú láti ra oúnjẹ fún ara wọn Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, Ẹ fún wọn ní oúnjẹ Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí fún pé, Eyí yóò ná wa tó owó iṣẹ́ lébìrà osù mẹ́jọ, Ṣe kí a lọ fi èyí ra búrẹ́dì fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí láti jẹ Jésù tún béèrè pé, Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ni lọ́wọ́ Ẹ lọ wò ó Wọ́n padà wá jíṣẹ́ pé, Ìṣù àkàrà márùn ún àti ẹja méjì Nígbà náà ni Jésù sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn náà kí a mú wọn jókòó lẹ́gbẹẹgbẹ́ lórí koríko Lẹ́sẹ̀kan-náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó, ní àádọ́ta tàbí ọgọgọọ́rùn-ún Nígbà tí ó sì mú ìsù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run Ó dúpẹ́ fún oúnjẹ náà, ó bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé e kalẹ̀ ṣíwájú àwọn ènìyàn náà àti àwọn ẹja méjì náà ni ó pín fún gbogbo wọn Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì kó agbọ̀n méjìlá tí ó kún fún àjẹkù àkàrà àti ti ẹja pẹ̀lú Àwọn tí ó sì jẹ́ àkàrà náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti padà sínú ọkọ̀ kí wọn sì ṣáájú rékọjá sí Bẹtisáídà Níbẹ̀ ni òun yóò ti wà pẹ̀lú wọn láìpẹ́ Nítorí òun fúnra a rẹ̀ yóò dúró sẹ́yìn láti rí i pé àwọn ènìyàn túká lọ ilé wọn Lẹ́yìn náà, ó lọ sórí òkè láti lọ gbàdúrà Nígbà tí ó dalẹ́, ọkọ̀ wà láàrin òkun, òun nìkan sì wà lórí ilẹ̀ Ó rí i wí pé àwọ́n ọmọ-ẹyin wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá, ṣùgbọ́n nígbà tí wọn rí i tí ó ń rìn, wọ́n rò pé ìwin ni Wọ́n sì kígbe sókè lohún rara, nítorí gbogbo wọn ni ó rí i, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n Ṣùgbọ́n òun sọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, Ẹ mú ọkàn le! Emi ni Ẹ má bẹ̀rù Nígbà náà ni ó gòkè sínú ọkọ̀ pẹ̀lú wọn, ìjì líle náà sì dáwọ́ dúró Ẹ̀rù sì bà wọ́n rékọjá gidigidi nínú ara wọn, ẹnú sì yà wọ́n Wọn kò sá à ronú iṣẹ́ ìyanu ti ìṣù àkàrà, nítorí ti ọkàn wọn yigbì Lẹ́yìn tí wọ́n la òkun náà kọjá, wọ́n gúnlẹ̀ sí Génésárétì Wọ́n sì so ọkọ̀ sí èbúté Wọ́n jáde kúrò nínú ọkọ̀ Àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀ rí Jésù, wọ́n sì dá a mọ̀ ọ́n Wéré, wọ́n ròyìn dídé rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn sáré gbé gbogbo àwọn aláìsàn wá pàdé rẹ̀ Ní ibi gbogbo tí ó sì dé, yálà ní abúlé, ìlú ńlá tàbí àrọ́ko, ńṣe ni wọ́n ń kó àwọn aláìsàn pàdé rẹ̀ ní àárin ọjà Wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí wọn fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ kàn án ni a mú láradá Mímọ́ àti Àìmọ́ Ní ọjọ́ kan, àwọn Farisí olùkọ́ àti àwọn òfin tí ó wá láti Jerúsálémù péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, Wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́ Nítorí èyí àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Èése tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn àṣà wa àtijọ́ nítorí wọ́n jẹun láì kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ wọn Jésù dá wọn lóhùn wí pé, Ẹyin àgàbàgebè yìí, òótọ́ ni wòlíì Àìṣáyà ń sọ nígbà tí ó ń ṣe àpèjúwe yín, tó wí pé  Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi Ìsìn wọn jẹ́ lásán, ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkì dá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apákan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àà àwọn ènìyàn Ó si wí fún wọn Ẹyin sáà mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ Mósè fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ Ó tún sọ pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni Ṣùgbọ́n ẹyin wá yí i po pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kó bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí a sọ fún wọn pé, Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí, nítorí tí mo ti fi èyí tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò si jẹ́ kí ó ṣe ohunkóhun fún baba tàbí iyá rẹ̀ mọ́ Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti yín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe Lẹ́yìn náà, Jésù pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ Ó sì wí fún wọn pé, Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́ Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́ Nígbà tí Jésù sì wọ inú ilé kan lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tẹ̀lé é, wọ́n sì béèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó pa Jésù béèrè wí pé, Àbí kò sí èyí tí ó yé yín nínú ọ̀rọ̀ náà Ẹ̀yin kò rí i wí pé ohunkóhun tí ó wọ inú ènìyàn láti òde kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́ Ìdí ni wí pé, Ohunkóhun tí ó bá wọ inú láti ìta, kò wọ inú ọkàn rárá, ṣùgbọ́n ó kọjá sí ikùn Nígbà náà, ó fi kún un pé Èyí ti ó ti ọkàn ènìyàn jáde ni ń sọni di aláìmọ́ Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà, ọ̀kánjúwà, odì-yíyàn, ìtànjẹ, ìmọ-tara ẹni, ìlara, ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀ Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́ Nígbà náà ni Jésù kúrò ní Gálílì, ó sí lọ sí agbégbé Tírè àti Sídónì, ó sì gbìyànjú láti nìkan wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, ṣùgbọ́n eléyìí kò ṣe é ṣe, nítorí pé kò pẹ́ púpọ̀ tí ó wọ ìlú nígbà tí ìròyìn dídé rẹ̀ tàn káàkiri Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jésù, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ Jésù Gíríkì ní obìnrin náà, Ṣíríàfonísíà ní orílẹ̀ èdè rẹ̀ Ó bẹ Jésù kí ó bá òun lé ẹ̀mí Èsù náà jáde lára ọmọbìnrin òun Jésù sọ fún obìnrin yìí pé, Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí a fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ lọ́rùn ná Nítorí kò tọ́ kí a mú oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá Obìnrin náà dáhùn wí pé, Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yín Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ajá pàápàá a máa ní àǹfààní láti jẹ ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tábílì Ó sì wi fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ Nígbà tí ó náà padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀ Nígbà náà ni Jésù fi agbégbé Tírè àti Ṣídónì sílẹ̀, ó wá si òkun Gálílì láàrin agbègbè Dékápólì Níbẹ̀ ọkùnrin kan tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Jésù, àwọn ènìyàn sì bẹ Jésù pé kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e Jésù sì mú ọkùnrin náà kúrò láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn Ó sì fi àwọn ìka rẹ̀ sí etí ọkùnrin náà, ó tu itọ sọ́wọ́ Ó sì fi kan ahọ́n rẹ̀ Nígbà náà ni Jésù wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, Éfátà, èyí ni, Ìwọ ṣí Bí Jésù ti pàṣẹ yìí tan, ọkùnrin náà sì gbọ́ràn dáadáa Ó sì sọ̀rọ̀ ketekete Jésù pàṣẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà níbẹ̀ pé kí wọn má ṣe tan ìròyìn náà ká Ṣùgbọ́n bí ó ti ń pa wọ́n lẹ́nu mọ́ tó, náà ni wọ́n ń tan ìròyìn náà káàkiri tó Àwọn ènìyàn sì kún fún ìyanu, wọ́n wí pé, Ó se ohun gbogbo dáradára, Ó mú kí adití gbọ́ràn, odi sì sọ̀rọ̀ Jésù Bọ́ Ẹgbàajì Ènìyàn Ní ọjọ́ kan, bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ, kò sí oúnjẹ fún wọn mọ́ láti jẹ Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Ó wí fún wọn pé, Àánú ọ̀pọ̀ ènìyàni wọ̀nyí ṣe mí nítorí pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti wà níhìn-ín, kò sì sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún wọn láti jẹ Bí mo bá sọ fún wọn láti máa lọ sí ilé wọn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ebi, wọn yóò dákú lójú-ọ̀nà, nítorí pé àwọn mìíràn nínú wọn ti ọ̀nà jínjìn wá Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè pé, Níbo ni a ó ti rí búrẹ́dì tí ó tó láti fibọ wọn nínú aṣálẹ̀ yìí Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Ìsù búrẹ́dì mélòó lẹ ní lọ́wọ́ Wọ́n fèsì pé, isu búrédì méje Nítori náà, ó pàsẹ fún àwọn ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀ Ó sì mú odindi búrédì méje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó pín wọ́n fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé ka iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ Wọ́n rí àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú Jésù tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọ́n fún àwọn ènìyàn náà Gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn náà ló jẹ àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn Lẹ́yìn èyí wọ́n kó àjẹkù ti ó kù jọ, agbọ̀n méje sì kún Àwọn tí ó jẹ ẹ́ tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ènìyàn, ó sì rán wọn lọ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn èyí, Jésù wọ inú ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí agbègbè Dálímánútà Àwọn Farisí tọ Jésù wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ Láti dán an wò, wọ̀n bèèrè fún àmì láti ọ̀run Jésù mí kanlẹ̀, nígbà tí ó gbọ́ ìbéèrè wọn Ó sì dáhùn wí pé, Èéṣe tí ìran yìí fi ń wá àmì Lóòtọ́ ni mo sọ fún un yín kò si àmì tí a ó fi fún ìran yín Nígbà náà ni ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi ó fi àwọn ènìyàn sílẹ̀, ó sì rékọjá sí apákejì òkun náà Sùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbàgbé láti mú búrédì tí yóò tó wọn ọ́n jẹ lọ́wọ́ Ẹyọ ìṣù búrédì kan ṣoṣo ni ó wà nínú ọkọ̀ wọn Bí wọ́n sì ti ń rékọjá, Jésù kìlọ̀ fún wọn pé, Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó ń mú búrẹ́dì wú àwọn Farisí àti ti Hẹ́rọ́dù Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú èyí láàrin ara wọn wí pé, Torí pé a kò mú búrédì lọ́wọ́ ni Jésù mọ ohun tí wọ́n sọ láàrin ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, Èése ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú búrẹ́dì lọ́wọ́ Ẹ̀yin kò kíyèsí i sì títí di ìsinyìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran Ẹyín ni etí ẹ kò sí gbọ́ran Ẹ̀yin kò sì rántí Nígbà ti mo bu ìṣù búrẹ́dì márùn ún fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣà jọ Wọ́n wí pé, Méjìlá Bákan náà, nígbà tí mo bọ́ ẹgbàajì pẹ̀lú ìṣù àkàrà méje, agbọ̀n mélòó ló kù sílẹ̀ lẹ́yìn àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn wọn Wọ́n dáhùn pé, Ó ku ẹ̀kún agbọ̀n méje Ó sì wí fún wọn pé, È é ha ti ṣe tí kò fi yé yin Nígbà tí wọ́n dé Bẹtisáídà, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ kàn án, kí ó sì wò ó sàn Jésù fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yin ìlú Ó tu itọ́ sí i lójú Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú náà Ó sì bi í léèrè pé, Ǹjẹ́ ìwọ lè rí ohunkóhun nísinsìn yìí Ọkùnrin náà wò àyíká rẹ̀, ó sì dáhùn pé, Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, mo rí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n n kò rí wọn kedere, wọ́n n rìn kiri bí àgékù igi Nígbà náà, Jésù tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere Jésù sì rán an sí àwọn ẹbí rẹ̀ Ó kìlọ̀ fún un pé, Má ṣe lọ sí ìlú, kí o má sì sọ fún ẹnikẹni ní ìlú Nisinsìn yìí, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Gálílì Wọ́n sì jáde lọ sí àwọn abúlé ní agbègbè Ṣísáríà Fílípì Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Ta ni àwọn ènìyàn rò wí pé mo jẹ́ Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà dáhùn pé, Àwọn kan rò pé ìwọ ni Jòhánù Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn sọ pé, ìwọ ni Èlíjà tàbí àwọn wòlíì mìíràn àtijọ́ ni ó tún padà wá ṣáyé Nígbà náà, Jésù bèèrè, Ta ni ẹ̀yin gan-an rò pé mo jẹ́ Pétérù dáhùn pé, Ìwọ ni Kírísítì náà Ṣùgbọ́n Jésù kìlọ̀ fún wọn, kí wọn má sọ èyí fún ẹnikẹ́ni Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé, Ọmọ Ènìyàn kò le má sàì jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin, a ó sì pa á, lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta yóò sì jíǹde Jésù bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Pétérù pe Jésù sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí Jésù yípadà, ó wo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Ó sì wí fún Pétérù pẹ̀lú ìtara pé, Kúrò lẹ́yìn mi Sátánì, nítorí ìwọ kò ro ohun tí Ọlọ́run bí kò ṣe ohun tí ènìyàn Nígbà náà ni Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó ṣe ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìyìn rere, òun náà ni yóò gbà á là Nítorí èrè kí ni ó jẹ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàsípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀ Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panságà àti ẹlẹ́sẹ̀ yìí, tí ó kún fún àìgbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, Ọmọ-Ènìyàn yóò tijú rẹ nígbà tí o bá padà dé nínú ògo Baba rẹ, pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì mímọ́ Ìparadà Ó sì wí fún wọn pé, Lóòtọ́ ni mo wí fún un yín àwọn mìíràn wa nínú àwọn tó dúró níhìnín yìí, tí kì yóò tọ́ ikú wò, títi yóò fi rí ìjọba Ọlọ́run tí yóò fi dé pẹ̀lú agbára Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Jésù sọ̀rọ̀ yìí, Jésù mú Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù lọ sí orí òkè gíga ní apákan Kò sí ẹlòmíràn pẹ̀lú wọn, ara rẹ̀ sì yípadà níwájú wọn Aṣọ rẹ̀ sì di dídán, ó sì funfun gbòò, tí alágbàfọ̀ kan láyé kò lè sọ di funfun bẹ́ẹ̀ Nígbà náà ni Èlíjà àti Mósè farahàn fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jésù Pétérù sì wí fún Jesù pé, Rábì, ó dára fún wa láti máa gbé níhìnín, si jẹ́ kí a pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fun ọ, ọ̀kan fún Mósè, àti ọ̀kan fún Èlíjà Nítorí òun kò mọ ohun tí òun ìba sọ, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi Ìkuukuu kan sì bò wọ́n, ohùn kan sì ti inú ìkúùkù náà wá wí pé Èyí ni àyànfẹ ọmọ mi Ẹ máa gbọ́ ti rẹ̀! Lójijì, wọ́n wo àyíká wọn, wọn kò sì rí ẹnìkan kan mọ́, bí kò ṣe Jésù nìkan ṣoṣo ni ó sì wà pẹ̀lú wọn Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jésù kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má ṣe sọ ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí Ọmọ-Ènìyàn yóò fi jíǹde kúrò nínú òkú Nítorí náà, wọ́n pa nǹkan náà mọ́ ní ọkàn wọn Ṣùgbọ́n wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ ara wọn ohun tí àjíǹde kúrò nínú òkú túmọ̀ sí Nísinsìnyìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, èéṣe tí àwọn olùkọ́-ófin ń sọ wí pé, Èlíjà ní yóò kọ́kọ́ dé Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, Lóòótọ́ ni Èlíjà yóò kọ́kọ́ dé yóò sì mú nǹkan gbogbo padà bọ̀ sípò Àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ nípa ti Ọmọ-Ènìyàn pé kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀ àti pé a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Èlíjà ti wa ná, wọ́n sì ti ṣe ohunkóhun tí ó wù wọ́n sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀ Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ pátápátá sí ẹ̀ṣẹ̀ òkè náà, wọ́n bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́sàn-án ìyókù ká Àwọn olùkọ́-òfin díẹ̀ sì ń bá wọn jiyàn Bí Jésù ti ń súnmọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pẹ̀lú ìbẹ̀rù, nígbà náà ni wọ́n sáré lọ kí i Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Kí ló fa àríyàn-jiyàn Ọkùnrin kan láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ Àti pé, nígbàkúùgbà tí ó bá mú un, á gbé e sánlẹ̀, a sì máa hó itọ́ lẹ́nu, a sì máa lọ́ ẹyín rẹ̀ Òun pàápàá a wá le gbàgìdì Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kí wọn lé ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, ṣùgbọ́n wọ́n kò lè ṣe é Ó sì dá wọn lóhun, ó wí pé, Ẹ̀yin ìran aláìgbàgbọ́ yìí, Èmi yóò ti bá a yín pẹ́ tó Èmi yóò sì ti mú sùúrù fún un yín pẹ́ tó Ẹ mú ọmọ náà wá sọ́dọ̀ mi Wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó sì rí i, lójúkan-náà ẹ̀mi náà nà án tàntàn ó sì ṣubú lulẹ̀, ó sì ń fi ara yílẹ̀, ó sì ń yọ ìfófóò lẹ́nu Jésù béèrè lọ́wọ́ baba ọmọ náà pé, Ó tó ìgbà wo tí ọmọ rẹ̀ ti wà nínú irú ipò báyìí Baba ọmọ náà dáhùn pé, Láti kékeré ni Nígbàkúùgbà ni ó sì máa ń gbé e sínú iná ati sínú omi, láti pa á run, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣàánú fún wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́ Jéṣù sì wí fún un pé, Bí ìwọ bá le gbàgbọ́ ohun gbogbo ni ó seé ṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́   Lójúkan-náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́ Nígbà tí Jésù rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń péjọ sọ́dọ̀ wọn, ó bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí pé, Ìwọ ẹ̀mí àìmọ́, adití àti odi, mo pàṣẹ fún ọ, kí ó jáde kúrò lára ọmọ yìí, kí ó má ṣe padà sí ibẹ̀ mọ́ Òun sì kígbe ńlá, ó sì nà án tàn tàn, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀ ọmọ náà sì dàbí ẹni tí ó kú tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ké wí pé, Héè, ọmọ náà ti kú Ṣùgbọ́n Jésù fà á lọ́wọ́, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ Ó díde dúró Nígbà tí ó sì wọ ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í léèrè ní kọ́kọ́ wí pé, Èéṣe tí àwa kò fi lè lé e jáde Ó sì wí fún wọn pé, Irú èyí kò le ti ipa ohun kan jáde, bí kò se nípa àdúrà Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n gba Gálílì kọjá Níbẹ̀ ni Jésù ti gbìyànjú láti yẹra kí ó bá à lè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí ó lè ráàyè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ sí i Nítorí o kọ̀ awọn Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, o si wí fun wọn pe, A o fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́, wọn ó sì pa á, lẹ́yìn ìgbà tí a bá sì pa á tan yóò jíǹde ní ijọ́ kẹta Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ìtumọ̀ ohun tí ó sọ náà Wọ́n dé sí Kapanámù Lẹ́yìn tí wọ́n sinmi tan nínú ilé tí wọ́n wọ̀, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, Kí ni ohun tí ẹ́ ń bá ara yín jiyàn lé lórí Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ nítorí wọn ti ń bá ara wọn jiyàn pé ta ni ó ga jùlọ láàrin àwọn Ó jókòó, ó sì pè àwọn méjìlá náà, ó sọ fún wọn pé, Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ẹni ìṣáájú, òun ni yóò ṣe ẹni ìkẹyìn gbogbo wọn Ó ní láti jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó fi sáàárín wọn, nígbà tí ó sì gbé e sí apá rẹ̀, ó wí fún wọn pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ́wọ́gba ọmọ kékeré bí èyí ní orúkọ mi, òun gbà mí Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mi, ó gba Baba mi, tí ó rán mi Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jòhánù, sọ fún un ní ọjọ́ kan pé, Olùkọ́, àwá rí ọkùnrin kan, tí ń fi orúkọ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí àìmọ̀ jáde, ṣùgbọ́n a sọ fún un pé kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí kì í ṣe ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ wa Jésù sì sọ fún un pé, Má ṣe dá irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ dúró, nítorí kò sí ẹnìkan ti ó fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóò tún lè máa sọ ohun búburú nípa mi Nítorí ẹni tí kò bá kọ ojú ìjà sí wa, ó wà ní ìhà tiwa Lóòótọ́ ni mo sọ fún ún yín bí ẹnikẹ́ni bá fún un yín ní ife omi kan nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kírísítì, dájúdájú ẹni náà kì yóò sọ èrè rẹ̀ nù bí ó ti wù kí ó rí Ṣùgbọ́n ti ẹnikẹ́ni bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ sìnà nínú ìgbàgbọ́ rẹ́, ó sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ni ọ̀run, kí a sì sọ ọ́ sínú òkun Bí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o gbé títí ayé àìnípẹ̀kun pẹ̀lú ọwọ́ kan ju kí a gbé ọ sínú iná àjóòkú ọ̀run àpáàdì pẹ̀lú ọwọ́ méjèèjì Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú tí iná nàá kì í kú Bí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé é sọnú, ó sàn kí ó di agẹ́sẹ̀, kí o sì gbé títí ayé àìnípẹ̀kun ju kí o ní ẹṣẹ̀ méjì tí ó gbé ọ lọ sí ọ̀run àpáàdì Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú, tí iná nàá kì í sì í ku Àti pé, bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn kí o wọ ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ojú kan ju kí ó ní ojú méjì kí ó sì lọ sí inú iná ọ̀run àpáàdì Níbi ti  kòkòrò wọn kìí kú,, tí iná kì í sì í kú Níbẹ̀ ni a ó ti fi iná dán ẹnìkọ̀ọ̀kan wò Iyọ̀ dára, ṣùgbọ́n tí ó bá sọ agbára adùn rẹ̀ nù, báwo ni ẹ ṣè lè padà mu un dùn Ẹ ni iyọ̀ nínú ara yín, ki ẹ sì máa gbé ni àlàáfíà pẹ̀lú ara yín Ìbínú Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ nípa Nínéfè Ìwé ìran Náhúmù ará Elikósì Olúwa ń jowu, ó sì ń gbẹ̀san Olúwa ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú Olúwa ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láì jìyà Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú ààjà àti nínú ìjì, Ìkùùku sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀ Ó bá òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ Ó sí sọ gbogbo odò di gbígbẹ Báṣánì àti Kámẹ́lì sì rọ, Ìtànná Lébánónì sì rẹ̀ sílẹ̀ Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèkéé sì di yíyọ́, ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀, àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀ Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀ Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀ Rere ni Olúwa , ààbò ní ọjọ ìpọ́njú Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé e, Ṣùgbọn pẹ̀lú ìkún omi ńlá ní òun yóò fi ṣe ìparun ibẹ̀ dé òpin òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀ Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ lòdì sí Olúwa Òun yóò fi òpin sí i, Ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣù wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àkékù koríko gbígbẹ Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Nínéfè, ni ẹnìkan ti jáde wá tí ó ń gbérò ibi sí Olúwa ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú Báyìí ni Olúwa wí Bí wọ́n tilẹ̀ pé, tí wọ́n sì pọ̀ níye, Ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀, nígbà tí òun ó bá kọ́já Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Júdà, èmi kì yóò pọ́n ọ lójú mọ́ Nísinsin yìí ni èmi yóò já àjàgà wọn kúrò ní ọrùn rẹ èmi yóò já sẹkẹ́sẹkẹ̀ rẹ dànù Olúwa ti fi àṣẹ kan lélẹ̀ nítorí tìrẹ Nínéfè Ìwọ kì yóò ni irú ọmọ láti máa jẹ́ orúkọ rẹ mọ́, Èmi yóò pa ère fínfín àti ère dídà run tí ó wà nínú tẹ́ḿpílì àwọn ọlọ́run rẹ Èmi yóò wa ibojì rẹ, nítorí ẹ̀gbin ni ìwọ Wò ó, lórí àwọn okè, awọn ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìròyin ayọ wá, ẹni tí ó ń kéde àlàáfíà, Ìwọ Júdà, pa àṣẹ rẹ tí ó ní ìrònú mọ́, kí ó sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ Àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì gbógun tì ọ́ mọ́ Wọn yóò sì parun pátapáta Nínéfè Yóò Ṣubú Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Nínéfè pa ilé-ìsọ́ mọ́, ṣọ́ ọ̀nà náà di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le, múra gírí Olúwa yóò mú ọláńlá Jákọ́bù padà sípò gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Ísírẹ́lì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run, tí wọ́n sì ti run àwọn àjàrà wọn Asà àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì di pupa àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ̀nà ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán igi fìrì ni a ó sì mì tìtì Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà, wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárin ìgboro Wọn sì dàbí ètúfú iná tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná Òun yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ṣíbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn wọn sá lọ sí ibi odi rẹ̀, a ó sì pèsè ààbò rẹ̀ A ó sí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, a ó sì mú ààfin náà di yíyọ́ A pa á láṣẹ pé ìlú náà Èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni kí a kó ní ìgbèkùn lọ A ó sì mú un gòkè wá àti awọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò ti ohùn bí ti oriri, ṣe amọ̀nà rẹ̀, wọn a sì máa lu àyà wọn Nínéfè dàbí adágún omi, tí omi wọn sì ń gbẹ́ ẹ lọ Dúró! Dúró! ni wọ́n ó máa kígbe, ṣùgbọ́n ẹnikankan kì yóò wo ẹ̀yìn Ẹ kó ìkógun fàdákà! Ẹ kó ìkógun wúrà! Ìṣúra wọn ti kò lópin náà, àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́! Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro ọkàn pami, éekún ń lu ara wọn, ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́ àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wà àti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún, níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún ti ń rìn, àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù Kìnnìún pàápàá tẹ́rù fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì fún-un ní ọ́rùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀, Ó sì fi ohun pípa kún ibùgbé rẹ̀ àti ihò rẹ̀ fún ohun ọdẹ Kíyèsíi èmi dojú kọ ọ́, ni Olúwa awọn ọmọ ogun wí Èmi yóò sì fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jóná nínú èéfín, idà yóò sì jẹ ọmọ kìnnìún rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì run Èmi yóò sì ké ohun ọdẹ rẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé Ohùn awọn òjíṣẹ́ rẹ ni a kì yóò sì tán gbọ́ mọ́ Ìkìlọ̀ Fún Nínéfè Ègbé ni fún ìlú ẹ̀jẹ̀ nì, gbogbo rẹ̀ kún fún èké, àti olè, ìja kò kúrò! Ariwo pàṣán àti ariwo kíkùn kẹ̀kẹ́ ogun àti jíjó ẹṣin àti gbígbọ̀n kẹ̀kẹ́ ogun jìgìjìgì! Ológun orí ẹṣin ń fi ìgbónára ju ìdà wọn mọ̀nàmọ̀nà ọ̀kọ̀ rẹ̀ ti ń dán yanran sí òkè! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ní àwọn ẹni tí a pa, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú òkú kò si ni òpin àwọn ènìyàn sì ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn panṣágà àgbèrè tí ó rójú rere gbà, Iyá àjẹ́ tí ó sọ́ àwọn orilẹ̀-èdè di ẹrú nipa àgbèrè rẹ̀ àti àwọn ìdílé nipa ìṣe àjẹ́ rẹ̀ Èmi dojú kọ ọ́, ni Olúwa awọn ọmọ ogun wí Èmi ó si ká aṣọ ìtẹ́lẹ̀dì rẹ ní ojú rẹ, Èmi yóò sì fi ìhòòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara, èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́ èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà Kò sí ṣe pé, gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé, Nínéfè ṣòfò Ta ni yóò kẹ́dùn rẹ Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tébésì lọ, èyí tí ó wà ní ibi odò, Náílì tí omi sì yí káàkiri Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀, omi si jẹ́ odi rẹ̀ Etiópíà àti Éjíbítì ni agbára rẹ, kò sí ní òpin Pútì àti Líbíà ni àwọn olùgbèjà rẹ̀ Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùn o sì lọ sí oko ẹrú Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀ ní orí ìta gbogbo ìgboro Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin, gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara a ó si fi ọ́ pamọ́ ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà Gbogbo ilé-ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn Nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n, ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun Kíyè sí, Obínrin ni àwọn ènìyàn rẹ ní àárin! Ojú ibodè rẹ ní a ó sí sílẹ̀ gbagada, fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ iná yóò jó ilẹ̀ rẹ Ìwọ pọn omi de ìhámọ́, mú ile ìsọ́ rẹ lágbára sí i wọ inú amọ̀ kí o sì tẹ erùpẹ̀, kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run Idà yóò sì ké ọ kúrò, yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò, yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata, àní, di púpọ̀ bí eṣú! Ìwọ ti sọ àwọn oníṣòwò rẹ di púpọ̀ títí wọn yóò ṣe pọ̀ ju ìràwọ̀ oju ọ̀run lọ Kòkòrò na ara rẹ̀ ó sì fò lọ Àwọn aládé rẹ̀ dàbí eṣú, àwọn ọ̀gágun rẹ dàbí ẹlẹ́ǹgà ńlá, èyí ti ń dó sínú ọgbà la ọjọ́ òtútù, ṣùgbọ́n nígbà tí òòrùn jáde, wọ́n sá lọ ẹnìkan kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé wà Ìwọ ọba Ásíríà, àwọn olùṣọ àgùntàn rẹ̀ ń tòògbé awọn ọlọ́lá rẹ yóò máa gbé inú ekuru Rẹ àwọn ènìyàn rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè ńlá, tí ẹnikẹni kò sì kó wọn jọ Kò sì sí ohun tí ó lè wo ọgbẹ́ ẹ rẹ sàn ọgbẹ́ rẹ kun fún ìrora Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ ìròyìn rẹ yóò pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí ni orí ta ni, ìwà buburu rẹ kò ti kọjá nígbà gbogbo Àdúrà Nehemáyà Ọ̀rọ̀ Nehemáyà ọmọ Hakaláyà Ní oṣù kíṣíléfì ní ogún ọdún nígbà tí mo wà ní ààfin Ṣúṣánì, Hánánì, ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin mi wá láti Júdà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin kan, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù tí ó ṣẹ́kù tí wọn kò kó ní ìgbèkùn, àti nípa Jérúsálẹ́mù Wọ́n sọ fún mi pé, Àwọn tí ó kù tí a kó ní ìgbèkùn tí wọ́n sì pada sí agbégbé ìjọba wà nínú wàhálà púpọ̀ àti ẹ̀gàn Odi Jérúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀ a sì ti fi iná ṣun ẹnu ibodè rẹ̀ Nígbà tí mo gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo jókòó mo sì ṣunkún Mo ṣọ̀fọ̀, mo gbààwẹ̀, mo sì gbàdúrà fún ọjọ́ díẹ̀ níwájú Ọlọ́run ọ̀run Nígbà náà ni mo wí pé Olúwa , Ọlọ́run ọ̀run, Ọlọ́run tí ó tóbi tí ó sì ní ẹ̀rù, tí ó ń pa májẹ̀mu ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn tí ó fẹ́ẹ tí wọ́n sì ń pa àṣẹ mọ́ Jẹ́ kí etíì rẹ kí ó ṣi sílẹ̀, kí ojúù rẹ kí ó sì sí sílẹ̀ láti gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní iwájú rẹ ní ọ̀sán àti ní òru fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwa ọmọ Ísírẹ́lì àti tèmi àti ti ilé baba mi, tí a ti ṣẹ̀ sí ọ Àwa ti ṣe búburú sí ọ A kò sì pa àṣẹ ìlànà àti òfin tí ìwọ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ mọ́ Rántí ìlànà tí o fún Móṣè ìránṣẹ́ rẹ, wí pé, Bí ìwọ bá jẹ́ aláìṣòótọ́, èmi yóò fọ́n-ọn yín ká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá yípadà sí mi, tí ẹ bá sì pa àṣẹ mi mọ́, nígbà náà bí àwọn ènìyàn yín tí a kó ní ìgbèkùn tílẹ̀ wà ní jìnnà réré ìpẹ̀kun ọ̀run, èmi yóò kó wọn jọ láti ibẹ̀, èmi yóò sì mú wọn wá, sí ibi tí èmi ti yàn bí i ibùgbé fún orúkọ mi Àwọn ni ìránṣẹ́ rẹ àti ènìyàn rẹ àwọn tí ìwọ rà padà pẹ̀lú agbára ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára ńlá rẹ Olúwa , jẹ́ kí etíì rẹ sí sílẹ̀ sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ yìí, àti sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ní inú dídùn láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ Fún ìránṣẹ́ rẹ ní àṣeyọrí lónìí kí o sì síjú àánú wòó níwájú Ọkùnrin yìí, Nítorí tí náà mo jẹ́ agbé-kọ́ọ̀bù ọba, nígbà náà Àwọn tí ó fi èdìdì dìí ni Nehemáyà baálẹ̀, ọmọ Hakaláyà Ṣedekáyà Ṣeráyà, Aṣaráyà, Jeremáyà, Páṣùn, Ámáráyà, malikíjà, Hátúsì, Ṣebanáyà, málúkì, Hárímù, Meremótì, Obadáyà, Dáníẹ́lì, Gínétónì, Bárúkì, Mésúlámù, Ábíjà, Míjámínì, Mááṣáyà, Bílígáì àti Ṣémáyà Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà Àwọn ọmọ Léfì Jéṣúà ọmọ Aṣanáyà, Bínúyì ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hénédédì, Kádímélì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn Ṣébánáyà, Hódáyà, Kélítà, Péláyà, Hánánì, Míkà, Réhébù, Hásábáyà, Ṣákúrì, Ṣérébáyà, Ṣébánáyà, Hódáyà, Bánì áti Benínù Àwọn olórí àwọn ènìyàn Párósì, Páhátí-Móábù, Élámù, Ṣátù, Bánì, Búnì, Áṣígádì, Bébáyì Àdóníjà, Bígífáyì, Ádínì, Átérì, Heṣekáyà, Áṣúrì, Hódáyà, Háṣámù, Béṣáyì, Hárífì, Ánátótì, Nébáyì, Mágípíásì, Mésúlámù, Héṣírì Méṣésábélì, Ṣádókù, Jádúyà Pélátíyà, Hánánì, Hánáyà, Hóséà, Hananáyà, Háṣúbù, Hálóésì, Píléhà, Ṣóbékì, Réhúmù, Háṣábínà, Mááséyà, Áhíyà, Hánánì, Ánánì, Málúkù, Hárímù, àti Báánà Àwọn ènìyàn tó kù—àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn aṣọ́nà, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àjèjì nítorí òfin Ọlọ́run, papọ̀ pẹ̀lú ìyàwóo wọn, gbogbo ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, tí òye yé gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Móṣè ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfín Olúwa , wa mọ́ dáadáa A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíkáa wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ wá ní ọjọ́ ìsimi láti tà, àwa kò ní ràá ní ọwọ́ọ wọn ní ọjọ́ ìsimi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́ Àwa gbà ojúṣe láti máa pa àṣẹ mọ́ pé a ó máa san ìdámẹ́ta ṣékélì ní ọdọọdún fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa Nítorí oúnjẹ tí ó wà lóríi tábìlì nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun ṣíṣun ìgbà gbogbo nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsimi, ti àyájọ́ oṣù tuntun àti àṣè tí a yàn nítorí ọrẹ mímọ́ nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti ṣun lọ́ríi pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin Àwa tún gbà ojuṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé Olúwa Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ , ti gbogbo èṣo àwọn igi àti ti wáìnì túntún wa àti ti òróró wá sí yàrá ìpamọ́ ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Léfì, nítorí àwọn ọmọ Léfì ni ó ń gba ìdáwẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́ Àlùfáà tí o ti ìdílé Árónì wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Léfì yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìpamọ́ inú ilé ìṣúra Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, àti àwọn ọmọ Léfì gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ , wáìnì túntún àti òróró wá sí yàrá ìpamọ́ níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà-tí-ń ṣe-ìránṣẹ́-lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa rí dúró sí Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa Àwọn Olùgbé Tuntun Ní Jérúsálẹ́mù Nísinsinyìí àwọn olórí àwọn ènìyàn tẹ̀dó sí Jérúsálẹ́mù, àwọn ènìyàn tó kù sì dìbò láti mú ẹnì kọ̀ọ̀kan jáde nínú àwọn mẹ́wàá mẹ́wàá láti máa gbé ní Jérúsálẹ́mù, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án tó kù yóò dúró sí àwọn ìlúu wọn Àwọn ènìyàn súre fún gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn láti gbé ní Jérúsálẹ́mù Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jérúsálẹ́mù Nínú àwọn ọmọ Júdà Átaáyà ọmọ Úṣáyà ọmọ Ṣekaráyà, ọmọ Ámáráyà, ọmọ Ṣefatayà, ọmọ Máhálálélì, ìran Pérésì àti Maaṣeayà ọmọ Bárúkì, ọmọ Koli-Hóṣè, ọmọ Haṣaíyà, ọmọ Ádáyà, ọmọ Joiaribù, ọmọ Ṣekaráyà, ìran Ṣélà Àwọn ìran Pérésì tó gbé ní Jérúsálẹ́mù jẹ́ àádọ́rin lé nírínwó ó dín méjì alágbára ọkùnrin Nínú àwọn ìran Bẹ́ńjámínì Ṣálù ọmọ Mésúlámù, ọmọ Jóédì, ọmọ Pédáyà, ọmọ Kóláyà, ọmọ Maaṣéyà, ọmọ Itíélì, ọmọ Jéṣáyà, àti àwọn ọmọ ẹ̀yìnin rẹ̀, Gábáì àti Ṣáláì jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́jọ ọkùnrin Jóẹ́lì ọmọ Ṣíkírì ni olóórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn, Júdà ọmọ Haṣenuáyà sì ni olórí agbégbé kejì ní ìlú náà Nínú àwọn àlùfáà Jédáyà ọmọ Jóáríbù Jákínì Ṣéráyà ọmọ Hílíkáyà, ọmọ Mésúlámù, ọmọ Ṣádókì, ọmọ Méráótì, ọmọ Áhítúbì alábojútó ní ilé Ọlọ́run, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ní tẹ́ḿpìlì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́rinlélógún ọkùnrin Ádáyà ọmọ Jéróhámù, ọmọ Péláyà, ọmọ Ámísì, ọmọ Ṣakaráyà, ọmọ Pásúrì, ọmọ Málíkíjà, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé jẹ́ òjìlúgba ó lé méjì ọkùnrin Ámáṣíṣáì ọmọ Áṣárélì, ọmọ Áṣáì, ọmọ Méṣílémótì, ọmọ Ìmérì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkúnrin jẹ́ méjìdínláàdọ́je Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sábídíelì ọmọ Hágédólímù Láti inú àwọn ọmọ Léfì Ṣémáyà ọmọ Háṣúbù, ọmọ Ásíríkámù, ọmọ Háṣábíyà ọmọ Búnì Ṣábétaì àti Jóṣábádì, olórí méjì nínú àwọn ọmọ Léfì, àwọn tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀yìn àgbàlá ilé Ọlọ́run Mátaníyà ọmọ Míkà, ọmọ Ṣábídì, ọmọ Áṣáfì, adarí tí ó rí ṣáájú ìdúpẹ́ àti àdúrà Bákíbúkíyà ẹnìkejì láàrin àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ àti Ábídà ọmọ Ṣámúyà, ọmọ Gálálì, ọmọ Jédútúmù Àwọn ọmọ Léfì nínú ìlú mímọ́ jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́rin Àwọn aṣọ́nà Ákúbù, Tálímónì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n máa ń ṣọ́nà jẹ́ méjìléláàdọ́-sàn-án ọkùnrin Àwọn tó kù nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, wà ní gbogbo ìlúu Júdà, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìníi tirẹ̀ Àwọn ìránṣẹ́ẹ tẹ́ḿpílì ń gbé lórí òkè òfélì, Ṣíhà àti Gíṣípà sì ni alábojútó wọn Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ní Jérúsálẹ́mù ní Húsì ọmọ Bánì, ọmọ Hásábíà, ọmọ Mátaníyà ọmọ Míkà Húṣì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Áṣáfù tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọsìn ní ilé Ọlọ́run Àwọn akọrin wà ní abẹ́ àṣẹ ọba, èyí tí ó n díwọ̀n iṣẹ́ ojoojúmọ́ọ wọn Petaiayọ̀ ọmọ Meṣeṣabélì, ọ̀kan nínú àwọn Ṣérà ọmọ Júdà ní aṣojú ọba nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ènìyàn náà Fún ìletò pẹ̀lú oko wọn, díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn Júdà tí ń gbé Kíríátí-Ábà, àti àwọn ìletò agbégbé e rẹ̀, ní Díbónì àti ìletò rẹ̀, ní Jékábíṣéélì Ní Jéṣúà, ní Móládà, ní Bétípélétì Ní Háṣárì Ṣúálì, ní Bíáṣébà àti àwọn agbégbé rẹ̀ Ní Ṣíkílágì, ní Mékónà àti àwọn ìletò rẹ̀, ní Ẹni-rímónì, ní ṣórà, ní Járímútì, Ṣánóà, Ádúlámù àti àwọn ìletò o wọn, ní Lákísì àti àwọn oko rẹ̀, àti ní Ásékà àti awọn ìletò rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé láti Bíáṣébà títí dé àfonífojì Hínómì Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì láti Gébì ń gbé ní Míkímásì, Áíjà, Bétélì àti àwọn ìletò rẹ̀ Ní Ánátótì, Nóbù àti Ánáníyà, Ní Háṣórì Rámà àti Gítaímù, Ní Hádídì, Ṣébóimù àti Nébálátì, Ní Lódì àti Ónò, àti ní àfonífojì àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà Nínú ìpín àwọn ọmọ Léfì ni Júdà tẹ̀dó sí Bẹ́ńjámínì Àwọn Àlùfáà Àti Àwọn Ọmọ Léfì Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tí ó bá Ṣérúbábélì ọmọ Ṣéálítíélì àti Jéṣúà padà Ṣeraiáyà, Jeremáyà, Éṣírà, Ámáríyà, Málúkì, Hátúsì, Ṣekánáyà, Réhúmù, Mérémótì, Ídò, Gínétónì, Ábíjà, Míjámínì, Móádáyà, Bílígà, Ṣémááyà, Jóíáríbù, Jédááyà, Ṣálù, Ámókì, Hílíkíyà, àti Jédáyà Wọ̀nyí ni olóórí àwọn àlùfáà àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn ní ìgbà ayé e Jéṣúà Àwọn ọmọ Léfì ni Jéṣúà, Bínúì, Kádímálì, Ṣérébíà, Júdà àti Mátaníyà ẹ̀ni tí òun pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, ni àkóso orin ìdúpẹ́ Bákíbúkíyà àti Húnì, àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn dúró sí ìdojúkojú wọn nínú ìsìn Jéṣúà ni baba Jòíákímù, Jòíákímù ni baba Élíáṣíbù, Élíáṣíbù ni baba Jóíádà, Jóíádà ni baba Jònátanì, Jònátanì sì ni baba Jádúà Ní ìgbé ayé Jòíakímù, wọ̀nyí ni àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn àlùfáà ti ìdílé Ṣeráiáyà, Méráyà ti ìdílé Jeremáyà, Hananíyà ti ìdílé Éṣírà, Mésúlámù ti ìdílé Ámáráyà, Jéhóhánánì ti ìdílé Málúkì, Jònátanì ti ìdílé Ṣékánáyà, Jóṣéfù ti ìdílé Hárímù, Ádíná ti ìdílé Mérémótì Hélíkáyì ti ìdílé Ídò, Ṣekaráyà ti ìdílé Gínétónì, Mésúlámù ti ìdílé Ábíjà, Ṣíkírì ti ìdílé Míníámínì àti ti ìdílé Móádíà, Pílítaì ti ìdílé Bílígà, Ṣámúyà ti ìdílé Ṣémáyà, Jéhónátanì ti ìdílé Jóíáríbù, Máténáyì ti ìdílé Jédáíáyà, Húsì ti ìdílé Ṣálù, Káláyì ti ìdílé Ámókì, Ébérì ti ìdílé Hílíkíáyà, Háṣábíáyà ti ìdílé Jédáíáyà, Nétanẹ́lì Àwọn olóórí ìdílé àwọn ọmọ Léfì ní ìgbà ayé Élíáṣíbù, Jóíádà, Jóhánánì àti Jádúà, àti pẹ̀lú ti àwọn àlùfáà ni a kọ sílẹ̀ ní ìgbà ìjọba Dáríúsì ará a Páṣíà Àwọn olórí ìdílé láàrin àwọn ọmọ Léfì títí di àkókò Jóhánánì ọmọ Élíáṣíbù ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé ìtàn Àti àwọn olóórí àwọn ọmọ Léfì ni Háṣábáyà, Ṣérébáyà, Jéṣúà ọmọ Kádímíélì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n dúró ní ìdojúkojúu wọn láti ròyìn àti láti dúpẹ́, apá kan ń dá èkejì lóhùn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run Mátanáyà, Bákíbúkáyà, Ọbadáyà, Mésúlámù, Tálímónì àti Ákúbù ni aṣọ́nà tí wọ́n ń ṣọ yàrá ìpamọ́ ní ẹnu ibodè Wọ́n ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ìgbà ayé e Jóíákímù ọmọ Jéṣúà, ọmọ Jósádákì, àti ní ọjọ́ ọ Nehemáyà baálẹ̀ àti ní ọjọ́ọ Ẹ́sírà àlùfáà àti akọ̀wé Nígbà ìyàsímímọ́ odi Jérúsálẹ́mù a mú ọmọ Léfì jáde wá láti ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú wọn wá sí Jérúsálẹ́mù láti fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ pẹ̀lú orin ìdúpẹ́ àti pẹ̀lú ohun èlò orin síḿbálì, háápù àti dùùrù A kó àwọn akọrin náà jọ papọ̀ láti àwọn ìletò tí ó yí Jérúsálẹ́mù náà ká—láti àwọn abúlé Nétófátítì, Láti Bétì Gílígálì, àti láti àwọn agbègbè Gébà àti Ásímáfétì, nítorí àwọn akọrin ti kọ́ àwọn ìletò fún ra wọn ní agbégbé Jérúsálẹ́mù Nígbà tí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n ya àwọn ènìyàn sí mímọ́, àti ẹnu ibodè àti odi pẹ̀lú Mo sì tún yan àwọn olórí Júdà láti gun orí odi náà Mo sì tún yan àwọn ẹgbẹ́ akọrin ńlá méjì láti dúpẹ́ Àwọn kan yóò gòkè odi lọ sí apá ọ̀tún sí ọ̀nà ibodè Ààtàn Hósáyà àti ìdajì àwọn olórí Júdà tẹ̀lé wọn, Àwọn wọ̀nyí náà sì lọ pẹ̀lúu wọn, Áṣáráyà, Éṣírà, Mésúlámù, Júdà, Bẹ́ńjámínì, Ṣémáyà, Jeremáyà, Pẹ̀lú àwọn àlùfáà díẹ̀ pẹ̀lú ipè , pẹ̀lúu Ṣakaráyà ọmọ Jónátanì, ọmọ Ṣémáyà, ọmọ Matanáyà, ọmọ Míkáyà, ọmọ Ṣákúrì, ọmọ Áṣáfì, Àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀—Ṣémáyà, Áṣárélì, Míláláì, gíláláì, Mááì, Nétanélì, Júdà àti Hánánì—pẹ̀lú ohun èlò orin bí àṣẹ Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run Éṣírà akọ̀wé ni ó sáájúu wọn bí wọ́n ti ń tò lọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́ Ní ẹnu ibodè oríṣun wọ́n ti ń lọ tààrà sí ọ̀nà ní orí àtẹ̀gùn ìlú Dáfídì ní orí òkè tí ó kángun sí odi, wọ́n sì gba ẹ̀gbẹ́ ilée Dáfídì kọjá títí dé ẹnu ibodè omi ní ìhà ìlà oòrùn Àwọn ẹgbẹ́ akọrin kejì gba ọ̀nà òdì kejì lọ Mo tẹ̀lé wọn ní orí odi, pẹ̀lú ìdajì àwọn ènìyàn, kọjá ilé ìṣọ́ ìléru lọ sí odi fífẹ̀, Kọjá ẹnu ibodè Éúfúrẹ́mù ibodè Jéṣánà, ẹnu ibodè ẹja, ilé ìṣọ́ Hánánélì àti ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn—ún, títí dé ẹnu ibodè àgùntàn Wọ́n sì dúró ní ibodè ìṣọ́ Àwọn ẹgbẹ́ akọrin méjèèjì tí wọ́n dúpẹ́ wà ní ààyè nínú ilé Ọlọ́run, èmi náà sì dúró ní ààyè mi pẹ̀lú ìdajì àwọn ìjòyè, Àti àwọn àlùfáà—Élíákímù, Máṣéyà, Míníámínì, Míkáyà, Éliánáyì, Ṣaráyà àti Hananáyà pẹ̀lú àwọn ìpèe wọn Àti pẹ̀lú Maáṣéyà, Ṣémáyà, Éṣérì Àwọn ẹgbẹ́ akọrin ní abẹ́ ìṣàkóso Jéṣíráyà Ní ọjọ́ náà wọ́n rú ẹbọ ńlá, wọ́n ṣe àjọyọ̀ nítorí Ọlọ́run ti fún wọn ní ayọ̀ ńlá Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé sì yọ̀ pẹ̀lú A lè gbọ́ ariwo ayọ̀ tí ó jáde láti Jérúsálẹ́mù ní jìnnà réré Ní àkókò náà, a yan àwọn ènìyàn láti jẹ́ alábojútó yàrá ìkó ẹrù fún àwọn ọrẹ àkọ́so èso àti àwọn ìdámẹ́wàá Láti inú àwọn oko tí ó wà ní àyíká ìlú ni wọ́n ti ní láti mú wá sínú yàrá ìkó nǹkan sí ìpín tí òfin sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, nítorí inú un àwọn ará a Júdà yọ́ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ, Léfì tó ń ṣiṣẹ ìránṣẹ Wọ́n ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run wọn àti iṣẹ́ ìyàsímímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà, wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Dáfídì àti Sólómónì ọmọ rẹ̀ ti pa á láṣẹ fún wọn Ní ọjọ́ pípẹ́ ṣẹ́yìn ní ìgbà Dáfídì àti Áṣáfì, ni àwọn atọ́nisọ́nà, ti wà fún àwọn akọrin àti fún orin ìyìn àti orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run Nítorí náà ní ìgbà ayé Ṣérúbábélì àti Nehemáyà, gbogbo Ísírẹ́lì ni ó ń dá ìpín lójoojúmọ́ fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà Wọ́n sì tún yan ìpín mìíràn ṣọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Léfì tó kù àwọn ọmọ Léfì náà tún ya ìpín ti àwọn ọmọ Árónì sọ́tọ̀ fún wọn Àtúnṣe Ìkẹyìn Tí Nehemáyà Ṣe Ní ọjọ́ náà ni a ka ìwé Móṣè ṣókè sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn, nínú un rẹ̀ ni a ti rí i tí a kọ ọ́ sílẹ̀ pé a kò gbọdọ̀ gba àwọn aráa Ámónì tàbí àwọn aráa Móábù sí àárin ìjọ ènìyàn Ọlọ́run láéláé Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Bálámù ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn-ún lé wọn lórí Nígbà tí àwọn ènìyàn gbọ́ òfin yìí, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjòjì ènìyàn tí ó dara pọ̀ mọ́ wọn kúrò láàrin àwọn Ísírẹ́lì Ṣáájú èyí a ti fi Élíáṣíbù àlùfáà ṣe alákoṣo yàrá ìkó nǹkan ilé Ọlọ́run wa sí Ó súnmọ́ Tóbíyà pẹ́kípẹ́ki Ó sì ti pèsè yàrá ńlá kan fún un, èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀ fún ìtọ́jú ọrẹ ọkà, tùràrí àti àwọn ohun èlò tẹ́ḿpìlì àti ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró ti a fi lélẹ̀ bí ìlànà fún àwọn ọmọ Léfì, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà àti pẹ̀lúu gbogbo ọrẹ fún àwọn àlùfáà Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo èyí ń lọ lọ́wọ́, èmi kò sí ní Jérúsálẹ́mù, nítorí pé ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n Aritaṣéṣéṣì ọba Bábílónì ni mo padà tọ ọba lọ Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀, mo gba ààyè lọ́dọ̀ọ rẹ̀ Mo sì padà sí Jérúsálẹ́mù Níhìn-ín ni mo ti mọ̀ nípa onírúurú ohun búburú tí Élíásíbù ti ṣe ní ti pípèṣè yàrá fún Tóbíyà nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run Kò tẹ́ mi lọ́rùn rárá, mo kó gbogbo ohun èlò ìdílée Tóbíyà dà síta láti inú iyàrá náà Mo pàṣẹ kí wọn ya àwọn iyàrá náà sí mímọ́, mo sì kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run padà síbẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti tùràrí Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Léfì, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ẹ wọn Nígbà náà ni mo bá àwọn ìjòyè wí, mo sì béèrè lọ́wọ́ọ wọn pé, Èéṣe tí a fi kọ ilé Ọlọ́run sílẹ̀ Nígbà náà ni mo pè wọ́n jọ pọ̀, mo sì fi olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀ Gbogbo Júdà mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó—nǹkan sí Mo sì fi àlùfáà Ṣelemáyà, Ṣádókà akọ̀wé àti ọmọ Léfì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pedáyà ṣe alákóṣo àwọn yàrá ìkó—nǹkan sí Mo sì yan Hánánì ọmọ Ṣákúrì, ọmọ Mátanáyà bí olùrànlọ́wọ́ọ wọn Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a kà sí àwọn tó ṣé e gbẹ́kẹ̀lé Àwọn ni a yàn láti máa pín ohun èlò fún àwọn arákùnrin wọn Rántíì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o má sì ṣe gbàgbé ohun tí mo fi òtítọ́ ṣe fún ilé Ọlọ́run mi yìí àti fún iṣẹ́ ẹ rẹ̀ gbogbo Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Júdà tí wọ́n ń fún wáìnì ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé oríi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ ìsinmi Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà Àwọn ará Tírè ti ń gbé nínú un Jérúsálẹ́mù ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù àti fún àwọn ọmọ Júdà Mo bá àwọn ọlọ́lá Júdà wí, mo wí fún wọn pé, Èwo ni ohun búburú tí ẹ ń ṣe yìí ti ẹ ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ Ṣé àwọn baba ńlá yín kòha ti ṣe nǹkan kan náà tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo àjálù yìí wá oríi wa, àti sórí ìlú yìí Báyìí, ẹ̀yin tún ń ru ìbínú ṣókè síi sórí Ísírẹ́lì nípa bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ Nígbà tí ojú ọjọ́ ń bora ní ẹnu ibodè Jérúsálẹ́mù, ṣáájú ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí a ti àwọn ìlẹ̀kùn, kí wọn má sì sí i títí tí ọjọ́ ìsinmi yóò fi kọjá Mo yan àwọn ìránṣẹ́ẹ̀ mi láti ṣọ́ ẹnu ibodè, kí a má ba à lè gbé ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi Ṣíbẹ̀, àwọn tí ń tà àti àwọn tí ń rà sùn ẹ̀yìn odi Jérúsálẹ́mù ní ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀méjì Ṣùgbọ́n mo kìlọ̀ fún wọn pé, È é tí jẹ́ ti ẹ̀yin fi ń sùn ní ẹ̀yin odi ní òru Bí ẹ̀yìn bá tún dán an wò mọ́, èmi yóò fi ọwọ́ líle mú un yín Láti ọjọ́ náà lọ, wọn kò sì wá ní ọjọ́ ìsinmi mọ́ Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì pé kí wọn ya ara wọn sí mímọ́, kí wọn sì ṣọ́ ẹnu ibodè kí a lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ Tún rántíì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o sì fi àánú un rẹ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí i títóbi ìfẹ́ẹ̀ rẹ Ní ọjọ́ wọ̀n ọn nì, mo rí àwọn ọkùnrin Júdà tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin láti Áṣídódù, Ámónì àti Móábù Ìdajì àwọn ọmọ wọn ń sọ èdè Áṣídódù tàbí èdè ọ̀kan lára àwọn ènìyàn mìíràn tó kù, wọn kò sì mọ bí a ṣe ń ṣọ èdè Júdà Mo bá wọn wí mo sì gégùn-ún lé wọn lórí Mo lu àwọn ènìyàn díẹ̀ nínú un wọn mo sì fa irun oríi wọn tu Mo mú kí wọn búra ní orúkọ Ọlọ́run, kí wọn wí pé, Ẹ̀yin kì yóò fi àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó tàbí fún ẹ̀yin tìkáara yín Kìí ha á ṣe àwọn ìgbéyàwó bí irú èyí ni ọba Sólómónì fi dá ẹ̀ṣẹ̀ Láàrin àwọn orìlẹ̀ èdè, kò sí ọba kan bí i tirẹ̀ Ọlọ́run rẹ̀ féràn rẹ̀, Ọlọ́run sì fi jẹ ọba lóríi gbogbo Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àjòjì ti sọ ọ́ sínú òfin ẹ̀ṣẹ̀ Ǹjẹ́ ó ha yẹ kí àwa tún gbọ́ báyìí pé ẹ̀yin náà tún ń ṣe àwọn nǹkan tí ó burú jọjọ wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣe aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjòjì Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Jóíádà, ọmọ Élíásíbù olórí àlùfáà jẹ́ àna Ṣáńbálátì ará a Hórónì Mo sì lé e jáde kúrò lọ́dọ̀ mi Rántí, Ọlọ́run mi, nítorí wọ́n ti ba iṣẹ́ àlùfáà jẹ́ pẹ̀lú u májẹ̀mu iṣẹ́ àlùfáà àti ti àwọn Léfì Nítorí náà, mo ya àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì sí mímọ́ kúrò nínú un gbogbo ohun àjòjì, mo sì yan iṣẹ́ fún wọn, olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ẹ rẹ̀ Mo sì tún pèṣè fún ọrẹ, igi—pákó ní àkókò tí a yàn àti fún àwọn èso àkọ́so Rántíì mi fún rere, Ọlọ́run mi Aritaṣéṣéṣì Rán Nehemáyà Lọ Jérúsálẹ́mù Ní oṣù Níṣánì ní ogún ọdún ìjọba ọba Aritaṣéṣéṣì, nígbà tí a gbé wáìnì wá fún-un, mo gbé wáìnì náà mo fi fún ọba, Ìbànújẹ́ kò hàn ní ojú mi rí ní iwájúu rẹ̀ Nítorí náà ni ọba béèrè lọ́wọ́ mi pé Èéṣe tí ojú rẹ fi fàro nígbà tí kò rẹ̀ ọ́ Èyí kì í ṣe ohun mìíràn bí kò ṣe ìbànújẹ́ ọkàn Ẹ̀rù bà mí gidigidi, Ṣùgbọ́n mo wí fún ọba pé, Kí ọba kí ó pẹ́! È é ṣe tí ojú mi ko ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí a sin àwọn baba mi sí wà ní ahoro, tí a sì ti fi iná run àwọn ibodè rẹ̀ Ọba wí fún mi pé, Kí ni ìwọ ń fẹ́ Nígbà náà, ni mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run, mo sì dá ọba lóhùn pé, Ti ó bá wu ọba, tí ìránṣẹ́ rẹ bá sì rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí ó rán mi lọ sí ìlú náà ní Júdà ní bi tí a sin àwọn baba mi nítorí kí èmi lè tún un kọ́ Nígbà náà ni ọba, pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bi mí pé, Báwo ni ìrìnàjò náà yóò ṣe pẹ́ ọ tó, nígbà wo sì ni ìwọ yóò padà Ó dùn mọ́ ọba láti rán mi lọ, bẹ́ẹ̀ ni mo dá àkókò kan Mo sì tún wí fún-un pé, Tí ó bá wu ọba, kí ó fún mi ní lẹ́tà sí àwọn baálé agbégbé Éúfúrétè nítorí kí wọ́n báà lè jẹ́ kí n la ọ̀dọ̀ wọn kọjá lọ sí Júdà láìléwu Kí èmi sì gba lẹ́tà kan lọ́wọ́ fún Aṣafu, olùṣọ́ igbó ọba, nítorí kí ó lè fún mi ní igi láti fi ṣe àtẹ́rígbà fún ibodè ilé ìṣọ́ tẹ́ḿpìlì àti fún odi ìlú náà àti fún ilé tí èmi yóò gbé Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi wà lóríì mi, ọba fi ìbéèrè mi fún mi Bẹ́ẹ̀ ni mo lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baálẹ̀ Agèégbè Yúfúrátè mo sì fún wọn ní àwọn lẹ́tà ọba Ọba sì ti rán àwọn ológun àti àwọn ẹlẹ́ṣin ogun pẹ̀lúu mi Nígbà tí Ṣáńbálátì ará Hórónì àti Tòbáyà ará a Ámónì tí wọ́n jẹ́ ìjòyè gbọ́ nípa èyí pé, ẹnikan wá láti mú ìtẹ̀ṣíwájú bá àlàáfíà àwọn ará Ísírẹ́lì inú bí wọn gidigidi Mo sì lọ sí Jérúsálẹ́mù, lẹ́yìn ìgbà tí mo dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀ Èmi kò sì sọ fún ẹnikankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jérúsálẹ́mù Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lúu mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn Ní òru, mo jáde lọ sí àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jákálì àti sí ẹnu ibodè jààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun Nígbà náà ni mo lọ sí ẹnu ibodè oríṣun àti sí adágún omi ọba, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tó fún ẹranko mi láti kọjá Bẹ́ẹ̀ ni mo gòkè àfonífojì ní òru, mo ń wo odi Ní ìparí, mo padà ṣẹ́yìn, mo sì tún wọlé láti ibodè àfonífojì Àwọn olórí kò mọ ibi tí mo lọ tàbí mọ ohun tí mo ń ṣe, nítorí èmi kò tí ì sọ fún àwọn ará Júù tàbí àwọn àlùfáà tàbí àwọn ọlọ́lá tàbí àwọn ìjòyè tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn tí yóò máa ṣe iṣẹ́ náà Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé, Ṣé ẹ rí wàhálà tí a wọ̀ Jérúsálẹ́mù wà nínú ìparun, ibodè rẹ̀ ni a sì ti fi iná jó Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún odi Jérúsálẹ́mù mọ, àwa kò sì ní jẹ́ ẹni ẹ̀gàn mọ́ Èmi sì tún sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi àti ohun tí ọba ti sọ fún mi Wọ́n dáhùn wí pé, Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ àtúnmọ rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere yìí Ṣùgbọ́n nígbà tí Ṣáńbálátì ará a Hórónì, Tòbáyà ara olóyè Ámónì àti Géṣémù ará a Arábíyà gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì fi wá ṣe ẹ̀sín Wọ́n béèrè pé Kí ni èyí tí ẹ ń ṣe yìí Ṣé ẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni Mo dá wọn lóhùn, mo wí fún wọn pé, Ọlọ́run ọ̀run yóò fún wa ní àṣeyọrí Àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ láti tún un mọ, ṣùgbọ́n fún un yin, ẹ̀yin kò ní ìpín tàbí ipa tàbí ẹ̀tọ́ ohun kóhun tí ó jẹ mọ́ ìtàn ní Jérúsálẹ́mù Àwọn Tí Ó Mọ Odi Élíṣíbù olórí àlùfáà àti àwọn àlùfáà arákùnrin rẹ̀ lọ ṣiṣẹ́, wọ́n sì tún ibodè Àgùntàn mọ Wọ́n yà á sí mímọ́, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn dúró sí ibi tí ó yẹ, wọ́n mọ ọ́n títí dé ilé ìṣọ́ Ọgọ́rùn ún, èyí tí wọ́n yà sí mímọ́ títí dé ilé ìṣọ́ gíga Hánálélì Àwọn ọkùnrin Jẹ́ríkò sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Ṣákúrì ọmọ Ímírì sì mọ ní ẹ̀gbẹ̀ àwọn ọkùnrin Jẹ́ríkò Àwọn ọmọ Háṣénáyà ni wọ́n mọ Ìbodè Ẹja Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn rẹ̀, ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè e rẹ̀ sí ààyè e wọn Mérémótì ọmọ Úráyà, ọmọ Hákóṣì tún èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ẹ wọn mọ Ẹni tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni Mésúlámù ọmọ Bérékíà, ọmọ Méṣéábélì tún èyí ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ẹ wọn mọ Bákan ńaà ni ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Ṣádókù ọmọ Báánà náà tún odi mọ Èyí tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn ni àwọn ọkùnrin Tẹ́kóà tún mọ, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́lá kò ṣe àtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà lábẹ́ àwọn olórí wọn Jóádà ọmọ Páṣéà àti Mésúlámù ọmọ Béṣódáyà ni wọ́n tún ẹnu ibodè àtijọ́ ṣe Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn Lẹ́yìn in wọn ni àtúnṣe tún wà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin Gíbíónì àti Mísípà Mélátíà ti Gíbíónì àti Jádónì ti Mérónótì àwọn ibi tí ó wà lábẹ́ àṣẹ baálẹ̀ agbègbè Éfúrétè Úsíélì ọmọ Hariháyà, ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, tún ṣe àtúnṣe èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti Hananíyà, ọ̀kan lára awọn tí ó ń ṣe tùràrí, tún ṣe àtúnṣe èyí tí ó tún tẹ̀lé e Wọ́n mú Jérúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò títí dé Odi Gbígbòòrò Réfájà ọmọ Húrì, alákòóṣo ìdajì agbègbè Jérúsálẹ́mù, tún èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣe Ní ẹ̀gbẹ́ èyí Jédáyà ọmọ Hárúmáfì tún èyí tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ilé rẹ̀ mọ, Hátúsì ọmọ Háṣábínéjà sì tún tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ Málíkíjà ọmọ Hárímù àti Háṣúbù ọmọ Páhátì—Móábù tún ẹ̀gbẹ́ kejì ṣe àti Ilé-ìṣọ́ Ìléru Ṣálúmù ọmọ Hálọ́ésì, alákóṣo ìdajì agbégbé Jérúsálẹ́mù tún ti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ Ibodè Àfonífojì ni Hánúnì àti àwọn ará Ṣánóà tún mọ Wọ́n tún-un kọ́ wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn àti àwọn ide rẹ̀ sí ààyè rẹ̀ Wọ́n sì tún tún ẹgbẹ̀rún-ún kan ìgbọ̀nwọ odi mọ títí dé ẹnu ibodè ààtàn Ẹnu ìbodè Ààtàn ni Málíkíjà ọmọ Rákábù, alákóṣo agbégbé Bẹti-Hákérémù tún mọ Ó tún un mọ, ó sì gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìde rẹ̀ sí ààyè wọn Ẹnu Ìbodè Oríṣun ni Ṣálúnì ọmọ Kólí-Hóṣì, alákóṣo agbégbé Mísípà tún mọ Ó tún ún mọ, ó kan òrùlé e rẹ̀ yíká, ó gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ àwọn ìdáiùú ìlẹ̀kùn àti àwọn idẹ rẹ̀ ró sí ààyè wọn Ó tún tún odi Adágún Ṣílóámù mọ, ní ẹ̀gbẹ́ Ọgbà Ọba, títí dé àwọn àtẹ̀gùn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti ìlú Dáfídì Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Nehemáyà ọmọ Áṣíbúkù, alákóṣo ìdajì agbégbé Bétí Ṣúrì ṣe àtúnmọ dé ibì ọ̀ọ́kan ibojì Dáfídì, títí dé adágún omi àtọwọ́dá àti títí dé ilé àwọn alágbára Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ará a Léfì, ní abẹ́ ẹ Réhúmù ọmọ Bánì Lẹ́gbẹ̀ ẹ́ rẹ̀ ni Hásíábíà, alákóṣo ìdajì agbégbé Kéílà ṣe àtúnṣe fún agbégbé tirẹ̀ Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn arákùnrin wọn ṣe àtún-ṣe, Báfáyì ọmọ Hénádádì, alákóṣo àwọn ìdajì agbégbé kéílà Lẹ́yìn rẹ̀ ni Éṣérì ọmọ Jéṣúà, alákóṣo Mísípà, tún ìbò mìíràn ṣe, láti ibìkan tí ó kojú sí ibi gíga sí ilé-ìhámọ́ra títí dé orígun Lẹ́yìn rẹ̀ ni Bárúkù ọmọ Ṣábáyì fi ìtaa tún apá mìíràn ṣe, láti orígun dé ẹnu ọ̀nà ilé Élíáṣíbù olórí àlùfáà Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Mérémótì ọmọ Úráyà, ọmọ Hákósì tún apá mìíràn ṣe, láti ẹnu ọ̀nà ilé Élíáṣíbù títí dé òpin rẹ̀ Àtúnṣe tí a tún tún ṣe lẹ́yìn rẹ̀ ní àwọn àlùfáà ní àyíká agbègbè tún ṣe Lẹ́yìn wọn ni Bẹ́ńjámínì àti Háṣíbù tún èyí ti iwájú ilé wọn ṣe lẹ́yìn wọn ni, Ásáríyà ọmọ Máṣéyà ọmọ Ananíyà tún ti ẹ̀gbẹ́ ilé rẹ̀ ṣe Lẹ́yìn rẹ̀ ni Bínúì ọmọ Hénádádì tún apá mìíràn ṣe, láti ilé Ásáríyà dé orígun àti kọ̀rọ̀, àti Pálálì ọmọ Úṣáì tún ọ̀kánkán orígun ṣe àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde láti ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ààfin tòkè lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbégbé àwọn olùṣọ́ Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Pédáyà ọmọ Párósì àti àwọn ìránṣẹ́ẹ tẹ́ḿpìlì tí ó ń gbé ní òkè Ófélì ṣe àtúnṣe títí dé ibi ọ̀kánkán ibodè omi sí ìhà ìlà oòrùn àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde Lẹ́yìn wọn ni àwọn ènìyàn Tékóà tún apá mìíràn ṣe, láti ilé ìṣọ́ ńlá tí ó yọ sóde títí dé ògiri Ófélì Àwọn àlùfáà ni ó ṣe àtúnṣe òkè ibodè ẹsin ṣe, ẹnì kọ̀ọ̀kan ní iwájú ilée rẹ̀ Lẹ́yìn wọn, Ṣádókì ọmọ Ímérì tún ọ̀kánkán ilé rẹ̀ ṣe Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣémáyà ọmọ Ṣekanáyà, olùṣọ́ ibodè ìhà ìlà oòrùn ṣe àtúnṣe Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Hananáyà ọmọ Ṣelemáyà, àti Hánúnì ọmọ ẹ̀kẹfà Ṣáláfì, tún apá ibòmíràn ṣe Lẹ́yìn wọn ni, Mésúlámù ọmọ Berekáyà tún ọ̀kánkán ibùgbé e rẹ̀ ṣe Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Mákíjà, ọ̀kan nínú àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ṣe àtúnṣe títí dé ilé àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn oníṣòwò, ní ọ̀kánkán ibodè àyẹ̀wò títí dé yàrá òkè kọ̀rọ̀ àti láàárin yàrá òkè kọ̀rọ̀ àti ibodè àgùntàn ni àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà àti àwọn oníṣòwò tún ṣe Àtakò sí Àtún Kọ Odi Jerúsálẹ́mù Nígbà tí Ṣáńbálátì gbọ́ pé àwa ń tún odi náà mọ, ó bínú, ó sì bínú púpọ̀ Ó fi àwọn ará Júù ṣe ẹlẹ́yà, ó sọ níwájú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti níwájú àwọn ọmọ ogun Ṣamáríà pé, Kí ni àwọn aláìlera Júù wọ̀nyí ń ṣe yìí Ṣé wọn yóò mú odi wọn padà ni Ṣé wọn yóò rú ẹbọ ni Ṣé wọn yóò paríi rẹ̀ lóòjọ́ ni bí Ṣé wọ́n lè mú òkúta tí a ti ṣun láti inú òkítì padà bọ̀ sípò tí ó jóná bí wọ́n ṣe wà yẹn Tóbíyà ará Ámónì, ẹni tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wí pé, Ohun tí wọ́n ń mọ—bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ lásán bá gùn-ún sókè, yóò fọ́ odi òkúta wọn lulẹ̀! Gbọ́ ti wa, Ọlọ́run wa, nítorí àwa di ẹni ẹ̀gàn Dá ẹ̀gàn wọn padà sórí ara wọn Kí o sì fi wọ́n fún ìkógun ní ilẹ̀ ìgbékùn Má ṣe bo ẹ̀bi wọn tàbí wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nù kúrò níwájúú rẹ, nítorí wọ́n mú ọ bínú níwájú àwọn ọ̀mọ̀lé Bẹ́ẹ̀ ni àwa mọ odi náà títí gbogbo rẹ̀ fi dé ìdajìi gíga rẹ̀, nítorí àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ pẹ̀lúu gbogbo ọkàn an wọn Ṣùgbọ́n nígbà tí Ṣáńbálátì, Tóbíyà, àwọn ará Árábù, ará Ámónì, àti àwọn ènìyàn Áṣídódì gbọ́ pé àtúnṣe odi Jérúsálẹ́mù ti ga dé òkè àti pé a ti mọ àwọn ibi tí ó yá dí, inú bí wọn gidigidi Gbogbo wọn jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti wá bá Jérúsálẹ́mù jà àti láti dìde wàhálà sí í Ṣùgbọ́n àwa gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì yan olùṣọ́ ọ̀sán àti ti òru láti kojú ìhàlẹ̀ yìí Lákòókò yìí, àwọn ènìyàn Júdà wí pé, Agbára àwọn òṣìṣẹ́ ti dínkù, àlàpà púpọ̀ ni ó wà tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi le è mọ odi náà Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọ̀ta wa wí pé, Kí wọn tó mọ̀ tàbí kí wọn tó rí wa, àwa yóò ti dé àárin wọn, a ó sì pa wọ́n, a ó sì dá iṣẹ́ náà dúró Nígbà náà ni àwọn Júù tí ó ń gbé ní ẹ̀gbẹ́ẹ wọn wá sọ fún wa ní ìgbà mẹ́wàá pé, Ibikíbi tí ẹ̀yin bá padà sí, wọn yóò kọ lù wá Nítorí náà mo dá ènìyàn díẹ̀ dúró níbi tí ó rẹlẹ̀ jù lẹ́yìn odi ní ibi gbangba, mo fi wọ́n síbẹ̀ nípa àwọn ìdílée wọn, pẹ̀lú àwọn idà wọn, àwọn ọ̀kọ̀ wọn àti àwọn ọrun wọn Lẹ́yìn ìgbà tí mo wo àwọn nǹkan yíká, mo dìde mo sì wí fún àwọn ọlọ́lá àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tó kù pé, Ẹ má ṣe bẹ̀rù u wọn Ẹ rántí Olúwa , ẹni tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, kí ẹ sì jà fún àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn ìyàwó yín àti àwọn ilée yín Nígbà tí àwọn ọ̀ta wa gbọ́ pé àwa ti mọ ọ̀tá wọn àti wí pé Ọlọ́run ti bàájẹ́, gbogbo wa padà sí ibi odi, ẹnìkọ̀ọ̀kan sí ibi iṣẹ́ tirẹ̀ Láti ọjọ́ náà lọ, ìdajì àwọn ènìyàn ń ṣe iṣẹ́ náà, nígbà tí àwọn ìdajì tó kù múra pẹ̀lú ọ̀kọ̀, àṣà, ọrun àti ìhámọ́ra Àwọn ìjòyè sì pín ara wọn ṣẹ́yìn in gbogbo ènìyàn Júdà Àwọn ẹni tí ó ń mọ odi Àwọn tí ń ru àwọn ohun èlò ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú ọwọ́ kan, wọ́n sì fi ọwọ́ kejì di ohun ìjà mú, olúkúlùkù àwọn ọ̀mọ̀lé fi idàa wọn sí ẹ̀gbẹ́ẹ wọn bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ń fọn ìpè dúró pẹ̀lúù mi Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tó kù pé, Iṣẹ́ náà fẹ̀ ó sì pọ̀, a sì ti jìnnà sí ara wa púpọ̀ lórí odi Níbikíbi tí ẹ bá ti gbọ́ ohùn ìpè, ẹ da ara pọ̀ mọ́ wa níbẹ̀ Ọlọ́run wa yóò jà fún wa! Bẹ́ẹ̀ ni àwa ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àwọn ìdajì ènìyàn tí ó di ọ̀kọ̀ mú, láti òwúrọ̀ kùtùkùtù títí di ìgbà tí ìràwọ̀ yóò fi yọ Ní ìgbà náà mo tún sọ fún àwọn ènìyàn pé, Jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ dúró ní Jérúsálẹ́mù ní òru, nítorí kí wọn le jẹ́ ẹ̀ṣọ́ fún wa ní òru, kí wọn sì le ṣe iṣẹ́ ní ọ̀sán Bẹ́ẹ̀ ni èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi àti àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó wà pẹ̀lúù mi kò bọ́ aṣọ wa, olúkúlùkù wa ní ohun ìjà tirẹ̀, kó dà nígbà tí wọ́n bá ń lọ pọn omi Nehemáyà Ran Àwọn Aláìní Lọ́wọ́ Nísinsìn yìí àwọn ènìyàn àti àwọn ìyàwó wọn kígbe ńlá sókè sí àwọn Júù arákùnrin wọn Àwọn kan ń wí pé, Àwa àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wa pọ̀ kí àwa kí ó le è jẹ, kí a sì wà láàyè, a gbọdọ̀ rí oúnjẹ Àwọn mìíràn wí pé, Àwa ti fi oko wa ọgbà àjàrà wa àti ilé wa dógò kí àwa kí ó lè rí oúnjẹ ní àkókò ìyàn Ṣíbẹ̀ àwọn mìíràn wí pé, Àwa ní láti yá owó láti san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba lórí àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ ẹran ara kan àti ẹ̀jẹ̀ kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ìlú wa tí àwọn ọmọkùnrin wa sì dára bí í ti wọn, síbẹ̀ àwa ní láti fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wa ṣọfà Díẹ̀ nínú àwọn ọmọbìnrin wa ti wà lóko ẹrú náà, ṣùgbọ́n àwa kò ní agbára, nítorí àwọn oko àti ọgbà àjàrà wa ti di ti ẹlòmíràn Èmi bínú gidigidi nígbà tí mo gbọ́ igbe wọn àti àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí Mo rò wọ́n wò ní ọkàn mi mo sì fi ẹ̀ṣùn kan ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè Mo sọ fún wọn pé, ẹ̀yin ń gba owó èlé lọ́wọ́ àwọn ará ìlúu yín! Nítorí náà mo pe àpèjọ ńlá láti bá wọn wí Mo sì wí fún wọn pé Níbi tí àwa ní agbára mọ, àwa ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí a ti tà fún àwọn tí kì í ṣe Júù padà Nísinsìn yìí ẹ̀yìn ń ta àwọn arákùnrin yín, tí àwa sì tún ní láti rà wọ́n padà! Wọ́n dákẹ́, nítorí wọn kò rí ohun kóhun sọ Nítorí náà, mo tẹ̀ṣíwájú pé, Ohun tí ẹ̀ ń ṣe kò dára Kò ha yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run bí, láti yẹra fún ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn tí í ṣe ọ̀ta wa Èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú ń yá àwọn ènìyàn lówó àti oúnjẹ Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a dáwọ́ owó èlé gbígbà yìí dúró! Ẹ fún wọn ní oko wọn, ọgbà àjàrà wọn, ọgbà ólífì wọn àti ilée wọn pẹ̀lú owó èlé tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ọ wọn ìdá ọgọ́rùn-ún owó, oúnjẹ , wáìnì túntún àti òróró tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ọ wọn padà kíákíá Wọ́n wí pé, Àwa yóò dá a padà  Àwa kì yóò sì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ọ wọn mọ́ Àwa yóò ṣe bí o ti wí Nígbà náà mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè búra láti jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ti ṣe ìlérí Mo sì gbọn ìṣẹ́tí aṣọ mi, mo wí pé, Báyìí ni kí Ọlọ́run gbọn olúkúlùkù ènìyàn tí kò bá pa ìlérí yìí mọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ ìní i rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni kí a gbọn irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kí ó sì ṣófo! Gbogbo ìjọ ènìyàn sì wí pé Àmín, wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa Àwọn ènìyàn náà sì ṣe bí wọ́n ti ṣe ìlérí Síwájú sí í, láti ogún ọdún ìjọba Aritaṣéṣéṣì, nígbà tí a ti yàn mí láti jẹ́ baálẹ̀ wọn ní ilẹ̀ Júdà, títí di ọdún kejìlélọ́gbọ̀n ìjọba rẹ̀—ọdún méjìlá, èmi àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ baálẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn baálẹ̀ ìṣáájú—tí ó ti wà ṣáájú mi—gbe àjàgà wúwo lé àwọn ènìyàn lórí yàtọ̀ fún oúnjẹ àti wáìnì wọ́n sì tún gba ogójì ṣékélì fàdákà lọ́wọ́ wọn Kódà àwọn ìránṣẹ́ wọn tún jẹ gàba lóríi wọn Ṣùgbọ́n èmi kò ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run Dípò bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi jìn fún iṣẹ́ lórí odi yìí Gbogbo àwọn ènìyàn mi péjọ síbẹ̀ fún iṣẹ́ náà a kò sì gba ilẹ̀ kankan Síwájú sí í, àádọ́jọ àwọn Júù àti àwọn ìjòyè jẹun lóríi tábìlì mi, àti pẹ̀lú àwọn tí wọ́n wá bá wa láti àwọn orílẹ̀ èdè tí ó yí wa ká Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni a máa rí pèṣè màlúù kan, ààyò àgùntàn mẹ́fà àti adìyẹ fún mi àti lẹ́ẹ̀kan ní ọjọ́ mẹ́wàá ni wọ́n máa ń pèṣè onírúurú wáìnì tí ó pọ̀ fún mi Fún gbogbo èyí, èmi kò béèrè oúnjẹ baálẹ̀, nítorí ohun ti a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí pọ̀ jọjọ Rántí mi, Ọlọ́run mi, fún rere, nítorí fún gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún àwọn ènìyàn yìí Àwọn Ọ̀ta Kò Dawọ Àtakò Dúró Nígbà tí Sáńbálátì, Tòbáyà Géṣémù ará Árábíà àti àwọn ọ̀taa wa tó kù gbọ́ pé, mo ti tún odi náà mọ, kò sì sí àlàfo kankan tí ó ṣẹ́ kù nínú un rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ì tí ì rì àwọn ìlẹ̀kùn ibodè ní àkókò náà Ṣáńbálátì àti Géṣémù rán iṣẹ́ yìí sí mi pé Wá jẹ́ kí a jọ pàdé pọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìletò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ónò Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbérò láti ṣe mí ní ibi Bẹ́ẹ̀ ni mo rán oníṣẹ́ padà pẹ̀lú èsì yìí pé Èmi ń ṣe iṣẹ́ ńlá kan, èmi kò le è sọ̀kalẹ̀ wá Èéṣe tí iṣẹ́ náà yóò fi dúró, nígbà tí mo bá fi í sílẹ̀ tí mo sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá Wọ́n rán iṣẹ́ náà sí mi nígbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, mo sì fún wọn ní èsì bákan náà fún ìgbà kọ̀ọ̀kan Ní ìgbà kárùn-ún, Sáńbálátì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí mi pẹ̀lú irú iṣẹ́ kan náà, lẹ́tà kan tí a kò fi sínú apo ìwé wà ní ọwọ́ọ rẹ̀ tí a kọ sínú un rẹ̀ pé A ròyìn rẹ láàárin àwọn orílẹ̀ èdè—Géṣémù sì sọ pé, òtítọ́ ni, pé—ìwọ àti àwọn Júù ń gbérò láti ṣọ̀tẹ̀, nítorí náà ni ẹ ṣe ń mọ odi Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn yìí, ìwọ sì ń gbérò láti di ọba wọn àti pé ó ti yan àwọn wòlíì kí wọn lè kéde nípa rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù ọba kan wà ní Júdà! Nísinsìn yìí, ìròyìn yìí yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọba nítorí náà wá, jẹ́ kí a bá ara wa sọ̀rọ̀ Mo dá èsì yìí padà sí i pé Kò sí ohun kan nínú irú ohun tí ìwọ sọ tí ó ṣẹlẹ̀ ìwọ kàn rò wọ́n ní orí ara rẹ ni Gbogbo wọn múra láti dẹ́rù bà wá, wọ́n ń rò ó wí pé, Ọwọ́ wọn kò ní ran iṣẹ́ náà, àti wí pé wọn kò ní paríi rẹ̀ Ṣùgbọ́n mo gbàdúrà pé, Nísinsìn yìí Ọlọ́run fi agbára fún ọwọ́ mi Ní ọjọ́ kan mo lọ sí ilé Ṣemáyà ọmọ Deláyà, ọmọ Mehetabélì, ẹni tí a há mọ́ sínú ilé rẹ̀ Ó wí pé, Jẹ́ kí a pàdé ní ilé Ọlọ́run nínú un tẹ́ḿpìlì, kí o sì jẹ́ kí a pa àwọn ìlẹ̀kùn tẹ́ḿpìlì dé, nítorí àwọn ènìyàn ń bọ̀ láti pa ọ́, ní òru ni wọn yóò wá láti pa ọ́ Ṣùgbọ́n mo wí pé, Ǹjẹ́ ó yẹ kí irú ènìyàn bí èmi sá lọ Tàbí kí ènìyàn bí èmi sá lọ sínú tẹ́ḿpìlì láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là Èmi kò ní lọ! Èmi wòye pé Ọlọ́run kò rán-an, ṣùgbọ́n ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí mi nítorí Tòbáyà àti Sáńbálátì ti bẹ̀ẹ́ ní ọ̀wẹ̀ Wọ́n bẹ̀ẹ́ ní ọ̀wẹ̀ láti dẹ́rù bà mí nítorí kí èmi lè dẹ́ṣẹ̀ nípa ṣíṣe èyí, kí wọn lè bà mí lórúkọ jẹ́, kí n sì di ẹni ẹ̀gàn A! Ọlọ́run mi, rántí Tòbáyà àti Ṣáńbálátì, nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe kí o sì tún rántí Nóádáyà wòlíì obìnrin àti àwọn wòlíì tókù tí wọ́n ń gbérò láti dẹ́rù bà mí Bẹ́ẹ̀ ni a parí odi náà ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Élúlì , láàrin ọjọ́ méjìléláàdọ́ta Nígbà tí àwọn ọ̀ta wa gbọ́ èyí, gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó yí wa ká bẹ̀rù jìnnìjìnnì sì mú wọn, nítorí wọ́n wòye pé iṣẹ́ yìí di ṣíṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa Bákan náà, ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọlọ́láa Júdà ń kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà ránṣẹ́ sí Tòbáyà, èsì láti ọ̀dọ̀ Tòbáyà sì ń wá sí ọ̀dọ̀ wọn Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júdà ti mulẹ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ àna Ṣekenáyà ọmọ Árà ọmọ rẹ̀ Jéhóhánánì sì tún fẹ́ ọmọbìnrin Méṣúlámì ọmọ Bérékíyà ṣíwájú sí í, wọ́n túnbọ̀ ń ròyìn iṣẹ́ rere rẹ̀ fún mi, wọ́n sì ń sọ ohun tí mo sọ fún-un Tòbáyà sì ń kọ àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ sí mi láti dẹ́rù bà mí Àkọsílẹ̀ Orúkọ Àwọn Ìgbèkùn Tí Wọ́n Padà Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì rì àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn Léfì Mo fún Hánánì arákùnrin mi pẹ̀lú Hananáyà olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí Jérúsálẹ́mù, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòótọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ Mo sọ fún wọn pé, A kò gbọdọ̀ sí ìlẹ̀kùn Jérúsálẹ́mù títí oòrùn yóò fi mú Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn Ìlú náà tóbi ó sì ní ààyè, ṣùgbọ́n ènìyàn inú rẹ̀ kéré, a kò sì tí ì tún àwọn ilé inú rẹ̀ kọ́ Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì ti kó ní ìgbékùn Àkọsílẹ̀ Orúkọ Àwọn Ọkùnrin Ísírẹ́lì Àwọn ìran Párósì ẹgbàá ó lé méjìléláàádọ́sàn-án ti Ṣéfátayà, òjìdínrinwó ó lé méjìlá ti Árà, ẹgbẹ̀tàléláàdọ́ta ó lé méjì ti Páhátì—Móábù ẹgbàá mẹ́rìnlá ó lé méjìdínlógún ti Élámù, ẹgbàafà ó lé mẹ́rìnléláàdọ́ta ti Ṣátù, òjìlélẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún ti Ṣákáì, òjìdínlẹ́gbẹ̀rin ti Bínúì, òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́jọ ti Bébáì, ẹgbẹ̀ta ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n ti Áṣígádì, ẹgbẹ̀ta ó dín méjìdínlọ́gọ́rin ti Ádóníkámù, ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méje ti Bígífáyì, ẹgbàá ó lé mẹ́tadínláàdọ́rin ti Ádínì, àádọ́tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé márùn-ún ti Átérì, méjìdínlọ́gọ́rùn-ún ti Áṣúmù, ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́jọ ti Béṣáì, ọ̀rìndínírinwó ó lé mẹ́rin ti Árífù méjìléláàdọ́fà ti Gíbíónì, márùnúndínlọ́gọ́rùn-ún Àwọn ọkùnrin Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti Nétófà, igba ó dín méjìlélógún ti Ánátótì, méjìdínláàdóje ti Bẹti-Ásímáfétì, méjìlélógójì ti Kiriati-Jíárímù, Kífírà, àti Béérótì, ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta ti Rámà àti Gébà, ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún ti Míkímásì, méjìlélọ́gọ́fà ti Bẹ́tẹ́lì àti Áì, mẹ́talélọ́gọ́fà ti Nébò mìíràn, méjìléláàdọ́ta ti Élámù mìíràn, ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàdọ́ta ti Hárímù, ọ̀rìndínnírínwó ti Jẹ́ríkò, ọ̀tàdínnírínwó ó lé márùn-ún ti Lódì, Hádídì, àti Ónò, ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé ọ̀kàn ti Ṣénáà ẹgbáàjì ó dín àádọ́rin Àwọn Àlùfáà àwọn ìran Jédáyà ẹgbàá ó dín mẹ́tadínlọ́gbọ̀n ti Ímérì, ẹgbẹ̀rùn-ún ó lé méjìléláàdọ́ta ti Páṣúrì, ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tadínláàdọ́ta ti Hárímù ẹgbẹ̀rùn-ún ó lé mẹ́tadínlógún Àwọn Ìran Léfì àwọn ìran Jéṣúà mẹ́rìnléláàdọ́rin Àwọn akọrin àwọn ìran Áṣáfù, méjìdínláàdọ́jọ Àwọn Aṣọ́bodè àwọn ìran Ṣílámù, Átérì, Támónì, Ákúbù, Hátítà, àti Ṣóbáì, méjìdínlógóje Àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì Àwọn Aran Ṣíhà, Haṣúfà, Tábáótì, Kérósì, Ṣíà, Pádónì, Lébánà, Hágábà, Ṣámáyì, Hánánì, Gídélì, Gáhárì, Réáyà, Réṣínì, Nékódà, Gáṣámù, Úṣà, Fáṣíà, Béṣáì, Méhúnímù, Néfíṣésímù, Bábúkù, Hákúfà, Háhúrì, Básílítù, Méhídà, Hárísà, Bákósì, Ṣísérà, Témà, Néṣíà, àti Hátífà Àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì àwọn ìranṣẹ́ Ṣótaì, Ṣóférétì Pérídà, Jáálà, Dákónì, Gídélì, Ṣéfátíyà, Hatílì, Pókérítì-Héṣebáímù, àti Ámónì Àwọn ìránṣẹ́ ilé tẹ́ḿpìlì àti àwọn ìran ìránṣẹ́ Sólómónì jẹ́ irinwó dín mẹ́jọ Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti Tẹ́lì-mẹ́là, Tẹ́lì-Hásíhà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Ísírẹ́lì Àwọn ìran Déláyà, Tóbíyà àti Nékódà, jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì Lára àwọn àlùfáà ni àwọn ìran Hóbáíyà, Hákósì àti Básíláì Àwọn wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í nibẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́ Baálẹ̀, sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú un jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lúu Úrímù àti Tímímù yóò fi dé Gbogbo ìjọ ènìyàn tí wọ́n péjọ pọ̀ jẹ́ ẹgbàámọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀tàdínlẹ́gbaàrin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin ìbáákà wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún Ràkunmí wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rinlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin Díẹ̀ lára àwọn olóórí ìdílé náà kópa nínú un ṣíṣe iṣẹ́ náà Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún dírámásì wúrà, àádọ́ta bóòlù àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà Díẹ̀ lára àwọn olóórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ọ̀kẹ́ méjì dírámásì wúrà àti ẹgbọ̀kànlá mínà fàdákà Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì dírámásì wúrà, ẹgbẹ̀rùn-ún méjì mínà fàdákà àti ẹ̀tàdínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà Àwọn àlùfáà, àwọn Léfì, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì wà ní ìlúu wọn Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú ìlúu wọn, gbogbo àwọn ènìyàn kó ara wọn jọ bí ẹnìkan ní gbangba ìta níwájú Ibodè-Omi Wọ́n sọ fún Ẹ́sírà akọ̀wé pé kí ó gbé ìwé òfin Mósè jáde, èyí tí Olúwa ti pa láṣẹ fún Ísírẹ́lì Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje ni àlùfáà Ẹ́sírà gbé ìwé òfin jáde ní iwájú ìjọ ènìyàn, èyí tí ó jẹ́ àpapọ̀ ọkùnrin àti obìnrin àti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n le è gbọ́ ọ ní àgbọ́yé Ó kà á sókè láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán bí ó ti kọjú sí ìta ní iwájú Ibodè-Omi ní ojú u gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ènìyàn tó kù tí òye le è yé tí wọ́n wà níbẹ̀ Gbogbo ènìyàn sì fetísílẹ̀ sí ìwé òfin náà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀ Akọ̀wé Ẹ́sírà dìde dúró lórí i pẹpẹ ìdúrólé tí a fi igi kàn fún ètò yìí Ní ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ ọ̀tún ni Mátítayà, Ṣémà, Ánáyà, Úráyà, Hílíkáyà àti Máṣéíyà gbé dúró sí, ní ẹ̀gbẹ́ òsìi rẹ̀ ní Pédáíyà, Míṣíhẹ́lì, Málíkíjà, Hásúmù, Háṣábádánà, Ṣekaráyà àti Mésúlámù dúró sí Ẹ́sírà sí ìwé náà, gbogbo ènìyàn sì le rí í nítorí ó dúró níbi tí ó ga ju gbogbo ènìyàn lọ bí ó sì ti sí ìwé náà, gbogbo ènìyàn dìde dúró Ẹ́sírà yin Olúwa , Ọlọ́run alágbára gbogbo ènìyàn gbé ọwọ́ọ wọn sókè, wọ́n sì wí pé Àmín! Àmín! Nígbà náà ni wọ́n wólẹ̀ wọ́n sì sin Olúwa ní ìdojúbolẹ̀ Àwọn Léfì-Jéṣúà, Bánì, Ṣérébáyà, Jámínì, Ákúbù, Ṣábétaì, Hódáyà, Máséyà, Kélítà, Aṣaráyà, Jóṣábádì, Hánánì àti Pereláyà—kọ́ wọn ni òfin náà bí àwọn ènìyàn ṣe wà ní ìdúró síbẹ̀ Wọ́n kà láti inú ìwé òfin Ọlọ́run, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àlàyé kí ohun tí wọ́n kà bá à le yé àwọn ènìyàn yékéyéké Nígbà náà ni Nehemáyà tí ó jẹ́ baálẹ̀, Ẹ́sírà àlùfáà àti akọ̀wé, àti àwọn Léfì tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn wí fún gbogbo wọn pé, Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín Ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ tàbí sumkún Nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ti ń sunkún bí wọ́n ti ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ inú òfin náà Nehemáyà wí pé, Ẹ lọ kí ẹ gbádùn oúnjẹ tí ẹ yàn láàyò kí ẹ sì mú ohun dídùn, kí ẹ sì mú díẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn tí kò ní Ọjọ́ yìí, mímọ́ ni fún Olúwa wa Ẹ má ṣe banújẹ́, nítorí ayọ̀ Olúwa ni agbára yín Àwọn ọmọ Léfì mú kí gbogbo ènìyàn dákẹ́ jẹ́, wọ́n wí pé, Ẹ dákẹ́, nítorí mímọ́ ni ọjọ́ yìí Ẹ má ṣe banújẹ́ Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn lọ láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì fi ìpín oúnjẹ ránṣẹ́, wọ́n sì ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ ńlá, nítorí báyìí àwọn òfin tí a sọ di mímọ́ fun wọn ti yé wọn Ní ọjọ́ kejì oṣù náà, àwọn olórí, gbogbo ìdílé, àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, péjọ sọ́dọ̀ Ẹ́sírà akọ̀wé, wọ́n farabalẹ̀ láti fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ òfin Wọ́n ri ní àkọsílẹ̀ nínú ìwé òfin, èyí tí Olúwa ti pa ní àṣẹ nípaṣẹ̀ Mósè, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé inú àgọ́ ní àkókò àjọ àgọ́ oṣù keje àti kí wọn kéde ọ̀rọ̀ yìí, kí wọn sì tàn-án kálẹ̀ ní gbogbo ìlúu wọn àti ní Jérúsálẹ́mù Ẹ jáde lọ sí ìlú olókè, kí ẹ mú àwọn ẹ̀ka inú olífì àti ẹ̀ka igi olífì ìgbẹ́, àti láti inú máítílì, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ àti àwọn igi tí ó léwé dáradára wá, láti ṣe àgọ́—gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn jáde lọ, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀ka wá, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn sí orí òrùlé ara wọn, ní àgbàlá wọn àti ní àgbàlá ilé Ọlọ́run àti ní ìta gbangba lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè omi àti èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè Éúfúrémù Gbogbo ìjọ ènìyàn tí wọ́n padà láti ìgbèkùn kọ́ àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú un wọn Láti ọjọ́ Jóṣúà ọmọ Núnì títí di ọjọ́ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tí ì ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀ bí irú èyí Ayọ̀ ọ wọn sì pọ̀ Ẹ́sírà kà nínú ìwé òfin Ọlọ́run, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, láti ọjọ́ kìn-ín-ní dé ọjọ́ ìkẹyìn Wọ́n ṣe àjọyọ̀ àjọ náà fún ọjọ́ méje, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n ní àpèjọ, ní ìbámu pẹ̀lú òfin Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kan náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì péjọ pọ̀, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da eruku sórí ara wọn Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ya ara wọn ṣọ́tọ̀ kúrò nínú un gbogbo àwọn àlejò Wọ́n dúró ní ààyè e wọn, wọ́n sì ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn àti iṣẹ́ búburú àwọn baba wọn Wọ́n dúró sí ibi tí wọ́n wà, wọ́n sì fi ìdámẹ́rin ọjọ́ kà nínú ìwé òfin Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì tún fi ìdámẹ́rin mìíràn ní ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ní ṣíṣin Olúwa Ọlọ́run wọn Nígbà náà ni Jéṣúà, àti Bánì, Kádímíélì, Ṣebaníà, Bunnì, Ṣeribíà, Bánì àti Kénánì gòkè dúró lórí àwọn àtẹ̀gùn àwọn ọmọ Léfì, wọ́n si fi ohùn rara kígbe sí Olúwa Ọlọ́run wọn Nígbà náà ni àwọn ọmọ Léfì Jéṣúà, Bánì, Háṣábínéáyà, Ṣérébáyà, Hódáyà, Ṣébánáyà àti Pétaíáyà—wí pé Ẹ dìde ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó wà láé àti láéláé Ìbùkún ni fún orúkọ ọ̀ rẹ tí ó ní ògo, kí ó sì di gbígbéga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ Ìwọ nìkan ni Olúwa Ìwọ ni ó dá àwọn ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù àti àìlónkà ogun ọ̀run wọn, ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú un rẹ̀, àwọn òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú un wọn Ìwọ fún gbogbo wọn ní ìyè àìlónkà àwọn ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́ Ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run, tí ó yan Ábúrámù tí ó sì mú u jáde láti Úrì ti Kálídéà, tí ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ábúráhámù Ìwọ sì rí í pé ọkàn rẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí ọ, ìwọ sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú u rẹ̀ láti fi ilẹ̀ àwọn aráa Kénánì, Hítì, Ámórì, Pérísì, Jébúsì àti Gírígásì fún irú àwọn ọmọ rẹ̀ Ìwọ ti pa ìpinnu rẹ̀ mọ́ nítorí tí ìwọ jẹ́ olódodo Ìwọ rí ìpọ́njú àwọn baba ńlá wa ní Éjíbítì ìwọ gbọ́ igbe ẹkún un wọn ní òkun pupa Ìwọ rán iṣẹ́ àmì àti isẹ́ ìyanu sí Fáráò, sí gbogbo àwọn ìjòyèe rẹ̀ àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ẹ rẹ̀, nítorí ìwọ mọ ìwà ìgbéraga tí àwọn ará Éjíbítì hù sí wọn Ìwọ ra orúkọ fún araà rẹ, èyí tí ó sì wà títí di òní yìí Ìwọ pín òkun níwájúu wọn, nítorí kí wọn lè kọjá ní ìyàngbẹ ilẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ sọ àwọn tí ń lépa wọn sínú ibú, bí òkúta sínú omi ńlá Ní ọ̀sán ìwọ daríi wọn pẹ̀lú òpó ìkúùkú àti ní òru ni ìwọ daríi wọn pẹ̀lú òpó iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọn yóò gbà Ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá sí orí òkè Ṣínáì ìwọ bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run Ìwọ fún wọn ní ìlànà àti àwọn òfin tí ó jẹ́ òdodo tí ó sì tọ́ àti ìlànà tí ó dára Ìwọ mú ọjọ́ Ìsinmi rẹ mímọ́ di mímọ̀ fún wọn, o sì fún wọn ní àwọn ìlànà, àwọn àṣẹ àti àwọn òfin láti ọwọ́ọ Mósè ìránṣẹ́ẹ̀ rẹ Ìwọ fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n àti nígbà òrùngbẹ o fún wọn ní omi láti inú àpáta ó sì sọ fún wọn pé, kí wọ́n lọ láti lọ gba ilẹ̀ náà tí ìwọ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fi fún wọn Ṣùgbọ́n àwọn, baba ńláa wa, wọ́n ṣe ìgbéraga, wọ́n sì ṣe agídí, wọn kò sì tẹríba fún àwọn ìlànà rẹ Wọ́n kọ̀ láti fetí sílẹ̀, wọ́n sì kùnà láti rántí iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ṣe ní àárin wọn Wọ́n ṣe agídí, nínú ìṣọ̀tẹ̀ẹ wọn, wọ́n yan olórí láti padà sí oko ẹrúu wọn Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì, olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ Nítorí náà ìwọ kò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀, Kódà nígbà tí wọ́n yá ère dídá fún ara wọn, tí wọ́n sì wí pé, Èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè láti Éjíbítì wá tàbí nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì Nítorí àánú ńláà rẹ, ìwọ kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní ihà Ní ọ̀sán ọ̀pọ̀ ìkùùkuu kò kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn láti ṣe amọ̀nà an wọn, tàbí ọ̀pọ̀ iná láti tàn sí wọn ní òru ní ọ̀nà tí wọn yóò rìn Ìwọ fi ẹ̀mí rere rẹ fún wọn láti kọ́ wọn Ìwọ kò dá mánà rẹ dúró ní ẹnu wọn, ó sì fún wọn ní omi fún òrùngbẹ Fún ogójì ọdún ni ìwọ fi bọ́ wọn ní ihà wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, aṣọ wọn kò gbó bẹ́ẹ̀ ni ẹṣẹ̀ wọn kò wú Ìwọ fi àwọn ìjọba àti àwọn orílẹ̀ èdè fún wọn, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ náà fún wọ́n Wọ́n sì gba ilẹ̀ ọba Ṣíhónì aráa Hésíbónì àti ilẹ̀ ógù ọba Báṣánì Ìwọ ti mú àwọn ọmọ wọn pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ tí o ti sọ fún àwọn baba wọn pé kí wọn wọ̀, kí wọn sì jogún un rẹ̀ Àwọn ọmọ wọn wọ inú un rẹ̀, wọ́n sì gbà ilẹ̀ náà Ìwọ sì tẹ orí àwọn aráa Kénánì, tí ń gbé inú ilẹ̀ náà ba níwájúu wọn ó fi àwọn aráa Kénánì lé wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ọba wọn àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kí wọn ṣe wọn bí ó ti wù wọ́n Wọ́n gba àwọn ìlú olódì àti ilẹ̀ ọlọ́ràá wọ́n gba àwọn ilé tí ó kún fún onírúurú gbogbo nǹkan rere, àwọn kàǹga tí a ti gbẹ́, awọn ọgbà àjàrà, awọn ọgbà ólífì àti àwọn igi eléso ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ Wọ́n jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì sanra dáadáa wọ́n sì yọ̀ nínú oore ńlá rẹ Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àìgbọ́ràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ wọ́n gbàgbé òfin rẹ Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ, tí o fi gbà wọn ni ìyànjú pé kí wọn yí padà sí ọ wọ́n sì ṣe ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì Nítorí náà, ìwọ fi wọ́n lé àwọn ọ̀taa wọn lọ́wọ́, àwọn tí ó ni wọ́n lára Ṣùgbọ́n nígbà tí a ni wọ́n lára wọ́n kígbe sí ọ Ìwọ gbọ́ wọn láti ọ̀run wá àti nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, ìwọ fún wọn ní olùgbàlà, tí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wọn Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ti wà nínú ìsinmi, wọn a sì tún ṣe búburú lójùu rẹ Nígbà náà ni ìwọ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ sọ́wọ́ àwọn ọ̀ta kí wọ́n lè jọba lóríi wọn Nígbà tí wọ́n bá sì tún kígbe sí ọ, ìwọ a gbọ́ láti ọ̀run wá, àti nínú àánú rẹ ni ìwọ gbà láti ìgbà dé ìgbà Ìwọ kìlọ̀ fún wọn làti Padà sínú òfin rẹ, ṣùgbọ́n wọ́n hu ìwà ìgbéraga, wọ́n sì ṣe àìgbọ́ràn si àṣẹ rẹ Wọ́n sẹ̀ sí ìlànà rẹ, nípa èyí tí ènìyàn yóò yè tí wọ́n bá pa wọ́n mọ́ Nínú agídí ọkàn wọ́n kọ ẹ̀yìn sí ọ, wọ́n jẹ́ olóríkunkun wọn kò sì fẹ́ gbọ́ Fún ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ọdún ni ìwọ fi ní ṣùúrù pẹ̀lùu wọn Nìpa ẹ̀míì rẹ ni ìwọ kìlọ̀ fún wọn nípaṣẹ̀ àwọn wòlíì Síbẹ̀ wọn kò fi etí sílẹ̀, nìtorì náà ni ìwọ ṣe fi wọ́n lé àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́ Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, ìwọ kò mú òpin bá wọn tàbí kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú Ǹjẹ́ nítorí náà, Ọlọ́run wa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ó pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, má ṣe jẹ́ gbogbo ìnira yìí dàbí ohun kékeré ní ojúù rẹ—ìnira tí ó ti wá sóríi wa, sórí àwọn ọba wa àti àwọn olórí wa, sórí àwọn àlùfáà wa àti àwọn wòlíì, sórí àwọn baba wa àti sórí gbogbo ènìyàn rẹ̀, láti àwọn ọjọ́ àwọn ọba Áṣíríà wá títí di òní Ìwọ jẹ́ olódodo nínú ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa ìwọ sì ti ṣe òtítọ́, nígbà tí a bá ṣe búburú Àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, àwọn àlùfáà wa, àti àwọn baba wa kò tẹ̀lé òfin rẹ wọn kò fetí sílẹ̀ sí àṣẹ rẹ tàbí àwọn ìkìlọ̀ tí ìwọ fún wọn Àní nígbà tí wọ́n wà nínú ìjọba wọn, tí wọ́n ń gbádùn oore ńlá tí ìwọ fi fún wọn, ní ilẹ̀ tí ó tóbi tí ó sì lọ́ràá, wọn kò sìn ọ́ tàbí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburúu wọn Ṣùgbọ́n wò ó, àwa jẹ́ lónìí, àwa jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ tí ìwọ fún àwọn baba ńlá wa, nítorí kí wọn bá máa jẹ èṣo rẹ̀ àti ire mìíràn tí ó mú jáde Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkórèe rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọba tí ó fi ṣe olórí wa Wọ́n ń ṣe àkóso lóríi wa àti lórí ẹran wa bí ó ti wù wọ́n, àwa sì wà nínú ìpónjú ńlá Nítorí gbogbo èyí, a ń ṣe àdéhùn tí ó fẹṣẹ̀múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé, àwọn olórí ọmọ Léfì àwọn àlùfáà wọn wa sì fi èdìdì wọn dìí Ìkànìyàn Olúwa bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ihà Ṣínáì nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ó wí pé Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Ísírẹ́lì nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan Ìwọ àti Árónì ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ olórí ìdílé rẹ̀ láti ràn yín lọ́wọ́ Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí Láti ọ̀dọ̀ Rúbẹ́nì, Élísúrì ọmọ Ṣédéúrì Láti ọ̀dọ̀ Símónì, Ṣélúmíélì ọmọ Ṣúrísáddáì Láti ọ̀dọ̀ Júdà, Násónì ọmọ Ámínádàbù Láti ọ̀dọ̀ Íssákárì, Nítaníẹ́lì ọmọ Ṣúárì Láti ọ̀dọ̀ Ṣébúlúnì, Élíábù ọmọ Hélónì Láti ọ̀dọ̀ àwọn sọmọ Jósẹ́fù láti ọ̀dọ̀ Éfraimù, Elisámà ọmọ Ámíhúdì Láti ọ̀dọ̀ Mánásè, Gámáélì ọmọ Pedasúrù Láti ọ̀dọ̀ Bẹ́ńjámínì, Ábídánì ọmọ Gídíónì Láti ọ̀dọ̀ Dánì, Áhíésérì ọmọ Ámísádáì Láti ọ̀dọ̀ Áṣérì, Págíélì ọmọ Ókíránì Láti ọ̀dọ̀ Gáádì, Élíásàfu ọmọ Déúélì Láti ọ̀dọ̀ Náfítalì, Áhírà ọmọ Énánì Àwọn wọ̀nyìí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Ísírẹ́lì Mósè àti Árónì mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Ísírẹ́lì jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn Wọ́n sì se àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paṣẹ fún Mósè Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú ihà Ṣínáì Láti ìran Rúbẹ́nì tí í se àkọ́bí Ísírẹ́lì Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Rúbẹ́nì jẹ́ ẹgbàá mẹ́talélọ́gbọ̀n-ó-lé-ẹgbẹ̀ta Láti ìran Símónì Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀ya Símónì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún-ó-lé ọ̀ọ́dúnrún Láti ìran Gáádì Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ẹbí àti ìdílé wọn Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gáádì jẹ́ ẹgbàá-ó-lé-àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀jọ Láti ìran Júdà Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Júdà jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógójì-ó-lé-ẹgbẹ́ta Láti ìran Ísákárì Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Íṣákárì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógójì-ó-lé-irinwó Láti ìran Ṣébúlúnì Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Ṣébúlúnì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógún-ó-lé-egbéje Láti inú àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù Láti ìran Éfúráímù Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Éfúráímù jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Láti ìran Mánássè Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Mánásè jẹ́ ẹgbàá ẹ́rìndínlógún-ó-lé-igba Láti ìran Bẹ́ńjámínì Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógún-ó-lé-egbéje Láti ìran Dánì Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dánì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n-ó-lé-ẹẹ̀dẹ́gbẹ̀rin Láti ìran Ásérì Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Áṣérì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ Láti ìran Náfítalì Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún ó lé, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Náfítalì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n-ó-lé-egbéje Wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Mósè àti Árónì kà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí méjìlá fún Ísírẹ́lì, tí ẹnìkọ̀ọ̀kan sojú fún ìdílé rẹ̀ Gbogbo ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tó sì lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́-ó-lé-egbéjìdínlógún-dín-àádọ́ta, A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Léfì mọ́ àwọn ìyókù Nítorí Olúwa ti sọ fún Mósè pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ ka ẹ̀yà Léfì, tàbí kí o kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Dípò èyí yan àwọn ọmọ Léfì láti jẹ́ alábojútó àgọ́ Ẹrí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójú tó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀ṣíwájú, àwọn ọmọ Léfì ni yóò tu palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Léfì náà ni yóò ṣe é Ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀ Àwọn ọmọ Léfì yóò jẹ́ alábojútó àti olùtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà, kí ìbínú má ba à sí lára ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí àwọn ọmọ Léfì sì máa ṣe ìtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Fèrè-Ìpè Fàdákà Olúwa sọ fún Mósè pé Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o má a lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín Nígbà tí o bá fọn méjèèjì gbogbo ìjọ ènìyàn yóò pé ṣíwájú rẹ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náa ni àwọn olórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì yóò péjọ ṣíwájú rẹ Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì, àwọn ẹ̀yà tó pa ibùdó sí ìhà ìlà oòrùn ni yóò gbéra Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì kejì, ibùdó tó wà ní ìhà gúúsù ni yóò gbéra Ìpè ìdágìrì yìí ni yóò jẹ́ àmì fún gbígbéra Nígbà tí o bá fẹ́ pe ìjọ ènìyàn jọ, fun fèrè nìkan, má se fun ti ìdágìrì pẹ̀lú rẹ̀ Àwọn Ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni kí ó máa fun fèrè Èyí yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún yín àti fún ìran tó ń bọ̀ Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀ta tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè A ó sì ránti yín níwájú Olúwa , Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta yín Bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọjọ́ ayọ̀ yín, ní gbogbo àjọ yín àti ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yín, ni kí ẹ máa fun fèrè lórí ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà yín, wọn yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín Ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ní ọdún kejì ni ìkùukù kúrò lórí tabánákù Ẹ̀rí Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì gbéra kúrò ní ihà Sínáì wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùukù fi dúró sí ihà Páránì Wọ́n gbéra nígbà àkọ́kọ́ yìí nípa àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè Àwọn ìpín ti ibùdó Júdà ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Náṣónì ọmọ Ámínádábù ni ọ̀gágun wọn Nẹ̀taníẹ́lì ọmọ Ṣúárì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Ísákárì Élíábù ọmọ Hélónì ni ọ̀gágun ni ìpín ti ẹ̀yà Ṣébúlúnì Nígbà náà ni wọ́n sọ tabánákù kalẹ̀ àwọn ọmọ Gáṣónì àti Mérárì tó gbé àgọ́ sì gbéra Àwọn ìpín ti ibùdó ti Rúbẹ́nì ló gbéra tẹ̀le wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn Élísúrì ọmọ Sédúrì ni ọ̀gágun wọn Ṣélúmíélì ọmọ Surisádáì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Símónì Élíásáfì ọmọ Déúélì ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Gáádì Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kóhátì tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabánákù dúró kí wọn tó dé Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Éfúráímù ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn Elisámà ọmọ Ámíhúdì ni ọ̀gágun wọn Gàmálíélì ọmọ Pédásúrì ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Mánásè Ábídánì ọmọ Gídíónì ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì Lákòótan, àwọn ọmọ ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dánì lábẹ́ ọ̀págun wọn Áhíésérì ọmọ Ámíṣádárì ni ọ̀gágun wọn Págíélì ọmọ Ókíránì ni ìpín ti ẹ̀yà Ásérì, Áhírà ọmọ Énánì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Náfítanì Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tò jáde gẹ́gẹ́ bí ogun nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn Mósè sì sọ fún Hóbábì ọmọ Réúélì ará Mídíánì tí í se àna Mósè pé, A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, Èmi ó fi fún un yín Bá wa lọ àwa ó se ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún Ísírẹ́lì Ó sì dáhùn pé, Rárá, èmi kò ní bá yín lọ, mò ń padà lọ sí ilẹ̀ mi àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi Mósè sì sọ pé, Jọ̀wọ́ ma fi wá sílẹ̀, ìwọ mọ ibi tí a lè pa ibùdó sí nínú ihà, ìwọ yóò sì jẹ́ ojú fún wa Bí o bá báwa lọ, a ó sì pín fún ọ nínú ohun rere yówù tí Olúwa bá fún wa Wọ́n sì gbéra láti orí òkè Olúwa ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta Àpótí Ẹ̀rí Olúwa ń lọ níwájú wọn fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta yìí láti wá ibi ìsinmi fún wọn Ìkúùkù Olúwa wà lórí wọn lọ́sán nígbà tí wọ́n gbéra kúrò ní ibùdó Nígbàkigbà tí àpótí Ẹ̀rí bá gbéra Mósè yóò sì wí pé Dìdé, Olúwa ! Kí a tú àwọn ọ̀ta rẹ ká, kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sì sálọ níwájú rẹ Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá sinmi yóò wí pé Padà, Olúwa , Sọ́dọ̀ àwọn àìmọye ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ísírẹ́lì Kíkùn Àwọn Ènìyàn Àti Iná Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn ènìyàn ń ṣe àròyé nípa wàhálà wọn sí etíìgbọ́ Olúwa Ìbúnú Olúwa sì ru sókè nígbà tí ó gbọ́ àròyé yìí, Nígbà náà ni iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa bọ́ sí àárin wọn, ó sì run àwọn tó wà ní òpin ibùdó Nígbà náà ni àwọn ènìyàn kígbe sí Mósè, Mósè sì gbàdúrà sí Olúwa iná náà sì kú Wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Tàbérà torí pé iná láti ọ̀dọ̀ Olúwa jó láàrin wọn Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí tó wà láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́kúfẹ́ wọn fi ìtara bèèrè fún oúnjẹ mìíràn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún wí pé, Bí i pé kí á rí ẹran jẹ báyìí! Àwa rántí ẹja tí à ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ ní Éjíbítì, apálá, ègúsí, ewébẹ̀ àlùbọ́sà àti àwọn ẹ̀fọ́ mìíràn Ṣùgbọ́n báyìí gbogbo ara wa ti gbẹ, kò sí ohun mìíràn láti jẹ àfi mánà nìkan tí a rí yìí! Mánà náà dàbí èso koriáńdérì, ìrísí rẹ̀ sì dàbí oje igi Àwọn ènìyàn náà ń lọ káàkiri láti kó o, wọn ó lọ̀ ọ́ lórí ọlọ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó Wọ́n le ṣè é nínú ìkòkò tàbí kí wọn ó fi ṣe àkàrà, adùn rẹ̀ yóò sì dàbí adùn ohun tí a fi òróró ṣe Nígbà tí ìrì bá ṣẹ̀ sí ibùdó lórí ni mánà náà máa ń bọ́ pẹ̀lú rẹ̀ Mósè sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sunkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálukú ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀ Olúwa sì bínú gidigidi Inú Mósè sì bàjẹ́ pẹ̀lú Mósè sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, Kí ló dé tí o fi mú wàhálà yìí bá iráńṣẹ́ rẹ Kí ni mo ṣe tí n kò fi tẹ ọ lọ́rùn tí ìwọ fi di ẹrù àwọn ènìyàn wọ̀nyí lé mi lórí Èmi ni mo ha lóyún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí bí Àbí èmi ló bí wọn Tí ìwọ fi sọ fún mi pé, máa gbé wọn sí oókan àyà rẹ, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti máa ń gbe ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti búra láti fún àwọn bàbá ńlá wọn Níbo ni n ó ti rí ẹran fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí Nítorí wọ́n ń sunkún sí mi pé, Fún wa lẹ́ran jẹ́! Èmi nìkan kò lè dá gbé wàhálà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹrù wọn ti wúwo jù fún mi Bí ó bá sì ṣe pé báyìí ni ìwọ ó ṣe máa ṣe fún mi, kúkú pa mí báyìí, tí mo bá ti bá ojú rere rẹ pàdé—kí ojú mi má ba à rí ìparun mi Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé Mú àádọ́rin ọkùnrin nínú àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn tí o mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí àti olóyè láàrin àwọn ènìyàn wá sínú Àgọ́ Ìpàdé, kí wọ́n lé dúró níwájú mi Èmi ó sì sọ̀kalẹ̀ wá bá yín sọ̀rọ̀ níbẹ̀ Èmi ó sì mú nínú Ẹ̀mi tí ń bẹ lára rẹ láti fi sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí Wọn ó sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru àjàgà àwọn ènìyàn kí ó má ṣe pé ìwọ nìkan ni ó o máa ru àjàgà náà Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé Ẹ ya ara yín sí mímọ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀la, ẹ ó sì jẹ ẹran Nítorí pé Olúwa ti gbọ́ igbe ẹkún yín, èyí tí ẹ sun pé, Ìbá ṣe pé a lè rí ẹran jẹ ni! Ó sàn fún wa ní Éjíbítì jù báyìí lọ! Nítorí náà ni Olúwa yóò fi fún yín ní ẹran, ẹ ó sì jẹ ẹ́ Ẹ kò ní i jẹ ẹ́ fún ọjọ́ kan, ọjọ́ méjì, ọjọ́ márùn-ún, ọjọ́ mẹ́wàá tàbí ogúnjọ́ lásán, Ṣùgbọ́n fún odidi oṣù kan títí tí ẹran náà yóò fi máa yọ ní imú yín, tí yóò sì sú yín nítorí pé ẹ ti kẹ́gàn Olúwa tí ó wà láàrin yín, ẹ sì ti sunkún fún un wí pé, Kí ló dé tí a fi kúrò ní Éjíbítì gan-an    Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé, Mo wà láàrin ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ènìyàn ni ìrìnkirì, ó sì sọ pé, Èmi ó fún wọn ní ẹran láti jẹ fún oṣù kan gbáko! Ǹjẹ́ bí a tilẹ̀ pa àgbò ẹran àti ọmọ ẹran, yóò ha tó wọn bí Tàbí bí a tilẹ̀ pa gbogbo ẹja inú omi fún wọn, yóò wa tó bí Olúwa sì dá Mósè lóhùn pé, Ọwọ́ Olúwa ha kúrú bí Ìwọ yóò ri nísinsin yìí bóyá ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò ṣẹ tàbí kò ni í ṣẹ Mósè sì jáde, ó sọ ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn Ó mú àwọn àádọ́rin àgbààgbà Ísírẹ́lì dúró yí àgọ́ ká Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ìkúùkù ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lárá Ẹ̀mí tó wà lára Mósè sí ara àwọn àádọ́rin àgbààgbà náà, Ó sì sẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n ṣọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò ṣọtẹ́lẹ̀ mọ́ Àwọn ọkùnrin méjì, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Élídádì àti Médádì kò kúrò nínú àgọ́ Orúkọ wọn wà lára àádọ́rin àgbààgbà yìí ṣùgbọ́n wọn kò jáde nínú àgọ́ ṣíbẹ̀ Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sì ṣọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́ Ọmọkùnrin kan sì sáré lọ sọ fún Mósè pé, Élídádì àti Médádì ń ṣọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́ Jósúà ọmọ Núnì tí í ṣe ìránṣẹ́ Mósè, láti kékeré tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dáhùn pé, Mósè olúwa mi, dá wọn lẹ́kun! Mósè sì wí fún un pé, Àbí ìwọ ń jowú nítorí mi Ìbá ti wù mí tó, kí gbogbo àwọn ènìyàn Olúwa jẹ́ wòlíì, kí Olúwa si fi Ẹ̀mí rẹ̀ sí wọn lára! Mósè àti àwọn àgbààgbà yìí sì padà sínú àgọ́ Afẹ́fẹ́ sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì kó àparò wá láti inú òkun Ó sì dà wọ́n káàkiri gbogbo ibùdó ní ìwọ̀n gíga ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta sórí ilẹ̀, bí ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan ní gbogbo àyíká Ní gbogbo ọjọ́ náà àti òru, títí dé ọjọ́ kejì ni àwọn ènìyàn fi ń kó àparò yìí Ẹni tó kó kéré jù lọ kó ìwọ̀n hómérì mẹ́wáà, wọ́n sì sà wọ́n sílẹ̀ fún ara wọn yí gbogbo ibùdó Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹran náà sì wà láàrin eyín wọn, kó tó di pé wọ́n jẹ ẹ́, ìbínú Olúwa sì ru sí àwọn ènìyàn, ó sì pa wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn Torí èyí ni wọ́n ṣe pe ibẹ̀ ní Kíbírótì Hátafà nítorí pé níbẹ̀ ni wọ́n gbé sìnkú àwọn ènìyàn tó ní ọ̀kánjúà oúnjẹ sí Àwọn ènìyàn yóòkù sì gbéra láti Kíbírótì Hátafà lọ pa ibùdó sí Hásérótì wọ́n sì dúró nibẹ̀ Míríámù Ati Árónì Tako Mósè Míríámù àti Árónì sọ̀rọ̀ òdì sí Mósè nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiópíà Wọ́n sì wí pé, Nípa Mósè nìkan ni Olúwa ti sọ̀rọ̀ bí, kò ha ti ipa wa sọ̀rọ̀ bí Olúwa sì gbọ́ èyí Lẹ́ẹ̀kan náà ni Olúwa sọ fún Mósè, Árónì àti Míríámù pé, Ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, jáde wá sínú àgọ́ ìpàdé Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì jáde síta Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀wọ̀n ìkúùkù, ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó ké sí Árónì àti Míríámù Àwọn méjèèjì sì bọ́ ṣíwájú, Ó wí pé, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi Bí wòlíì Olúwa bá wà láàrin yín Èmi Olúwa a máa fara à mi hàn án ní ojúran, Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mósè ìránṣẹ́ mi ó jẹ́ olótítọ́ nínú gbogbo ilé mi Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú, ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe, ó rí àwòrán Olúwa Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò se bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ òdì sí Mósè ìránṣẹ́ mi Ìbínú Olúwa sì ru sókè sí wọn Olúwa sì fi wọ́n sílẹ̀ Nígbà tí ìkúùkù kúrò lórí àgọ́ lójijì ni Míríámù di adẹ́tẹ̀, ó funfun bí i yìnyín Árónì sì padà wo Míríámù ó sì rí i pé ó ti di adẹ́tẹ̀, Ó sì sọ fún Mósè pé, Jọ̀wọ́ olúwa mi, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí a fi ìwà òmùgọ̀ dá sí wa lọ́rùn Má ṣe jẹ́ kí ó dàbí òkú ọmọ tí a bí, tí ìdajì ara rẹ̀ ti rà dànù Torí èyí Mósè sì kígbe sí Olúwa , Olúwa , dákun mú un lára dá! Olúwa sì dá Mósè lóhùn, Bí bàbá rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ojú kò wa ní í tì í fún ọjọ́ méje Dá a dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn èyí ki a tó ó le mú wọlé Míríámù sì dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn ènìyàn kò sì tẹ̀ ṣíwájú nínú ìrìnàjò wọn títí tí Míríámù fi wọ inú ibùdó padà Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn kúrò ní Hásérótì, wọ́n sì pa ibùdó sí Aginjù Páránì Ṣíse Amí Sí Ilẹ̀ Kénánì Olúwa sọ fún Mósè pé, Rán ènìyàn díẹ̀ láti lọ yẹ ilẹ̀ Kénánì wò èyí tí mo ti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Rán ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ó jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan Mósè sì rán wọn jáde láti Aginjù Páránì gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì Orúkọ wọn nìwọ̀nyí láti inú ẹ̀yà Rúbẹ́nì Ṣámuá ọmọ Ṣákúrì láti inú ẹ̀yà Símónì, Ṣáfátì ọmọ Hórì láti inú ẹ̀yà Júdà, Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè Láti inú ẹ̀yà Ísíkárì, Ígálì ọmọ Jósẹ́fù Láti inú ẹ̀yà Éfúráímù, Ósíà ọmọ Núnì Láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Pálítì ọmọ Raù Láti inú ẹ̀yà Ṣébúlónì, Gádíélì ọmọ Ṣódì Láti inú ẹ̀yà Mánásè, , Gádì ọmọ Ṣúsì Láti inú ẹ̀yà Dánì, Ámíélì ọmọ Gémálì Láti inú ẹ̀yá Áṣérì, Ṣétúrì ọmọ Míkáẹ́lì Láti inú ẹ̀yà Náfítanì, Nábì ọmọ Fófósì Láti inú ẹ̀yà Gádì, Géúlì ọmọ Mákì Wọ̀nyí ni orukọ àwọn ènìyàn tí Mósè rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò Nígbà tí Mósè rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, ó sọ fún wọn pé, Ẹ gba ọ̀nà Gúúsù lọ títi dé àwọn ìlú olókè Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára Báwo ni ìlú wọn ti rí Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀ Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti Aginjù Ṣínì títí dé Réhóbù lọ́nà Lébò Hámátì Wọ́n gba Gúsù lọ sí Hébírónì níbi tí Áhímánì, Ṣésáì àti Tálímà tí í se irú ọmọ Ánákì ń gbé Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Éṣíkólù, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èṣo àjàrà gíréèpù kan Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e wọ́n tún mú èṣo pomegíránétì àti èṣo ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú Wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní àfonífojì Ésíkólù nítorí ìdí èso gíréépù tí wọ́n gé níbẹ̀ Wọ́n padà sílé lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí wọ́n ti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò Wọ́n padà wá bá Mósè àti Árónì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísiréli ní ijù Kádésí Páránì Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n Wọ́n sì fún Mósè ní ìròyìn báyìí A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóótọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èṣo ibẹ̀ nìyìí Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tó ń gbé níbẹ̀ lágbára, àwọn ìlú náà jẹ́ ìlú olódi bẹ́ẹ̀ ni ó sì tóbi púpọ̀ A tilẹ̀ rí àwọn irú ọmọ Ánákì níbẹ̀ Àwọn Ámálékì ń gbé ní ilẹ̀ Gúsù àwọn ará Hítì, àwọn ará Jébúsì àti àwọn ará Ámórì ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kénánì sì ń gbé ẹ̀bá òkun àti ní etí bèbè Jọ́dánì Kélẹ́bù sì pa àwọn ènìyàn náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mósè, ó wí pé, Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ lẹ́ẹ̀kan náà láti lọ gba ilẹ̀ náà, nítorí pé àwa le è gbà á Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ gòkè lọ yẹ ilẹ̀ wò sọ pé, Àwa kò le gòkè lọ bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí nítorí pé wọ́n lágbára jù wá lọ Báyìí ni wọ́n ṣe mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ tí wọ́n lọ yẹ̀ wò Wọ́n wí pé, Ilẹ̀ tí a lọ yẹ̀ wò jẹ́ ilẹ̀ tí ń run àwọn olùgbé ibẹ̀ Gbogbo àwọn ènìyàn tí a rí níbẹ̀ jẹ́ ènìyàn tó fìrìgbọ̀n tó sì sígbọnlẹ̀ A sì tún rí àwọn òmìrán àwa sì rí bí i kòkòrò tata ní ojú ara wa, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà sì rí ní ojú wọn Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Kọ̀ Láti Lọ Sí Kénánì Gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbóhùn sókè, wọ́n sì sunkún ní òru ọjọ́ náà Gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì sì kùn sí Mósè àti Árónì, gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì wí fún wọn pé Àwa ì bá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Éjíbítì Tàbí kí a kúkú kú sínú ihà yìí Kí ló dé tí Olúwa fi mú wa wá sí ilẹ̀ yìí láti fi idà pa wá , Àwọn ìyàwó wa, àwọn ọmọ wa yóò sì di ìjẹ Ǹjẹ́ kò wa, ní í dára fún wa bí a bá padà sí Éjíbítì Wọ́n sì sọ fún ara wọn pé Ẹ jẹ́ kí á yan olórí kí á sì padà sí Éjíbítì Nígbà náà ni Mósè àti Árónì dojú bolẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ọmọ Ísírẹ́lì Jóṣúà ọmọ Núnì àti Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè, tí wọ́n wà lára àwọn to lọ yẹ ilẹ̀ wò sì fa aṣọ wọn ya Wọ́n sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì pé, Ìlẹ̀ tí a là kọjá láti yẹ̀ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ Bí inú Olúwa bá dùn sí wa, yóò mú wa dé ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, yóò fún wa ní ilẹ̀ náà Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀tẹ̀ sí Olúwa Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú àwa, Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn Ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń sọ pé àwọn yóò sọ wọ́n lókúta pa Nígbà náà ni ògo Olúwa fara hàn ní Àgọ́ Ìpàdé níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Olúwa sọ fún Mósè pé Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo ṣe láàrin wọn Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ Ṣùgbọ́n Mósè sọ fún Olúwa pé, Nígbà náà ni àwọn ará Éjíbítì yóò gbọ́ Nítorí pé nípa agbára Írẹ ni ìwọ fi mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò láàrin wọn Wọ́n ó sì sọ fún àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí Àwọn tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ìwọ Olúwa wà láàrin àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti pé wọ́n rí ìwọ, Olúwa , ní ojúkojú, àti pé ìkùukùu àwọsánmọ̀ rẹ dúró lórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ń lọ níwájú wọn pẹ̀lú ìkùukùu àwọsánmọ̀ ní ọ̀sán àti pẹ̀lú ọ̀wọ́n iná ní òru Bí ìwọ bá pa àwọn ènìyàn wọ̀nyí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀ èdè tó bá gbọ́ ìròyìn yìí nípa rẹ yóò wí pé Nítorí pé Olúwa kò le è mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí dé ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn torí èyí ló ṣe pa wọ́n sínú ihà yìí Báyìí, mo gbàdúrà, jẹ́ kí agbára Olúwa tóbi gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣọ pé Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró sinsin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jìn Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin Dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yìí jìn wọ́n, mo bẹ̀ ọ́, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ, bí o ti ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n láti ìgbà tí o ti kó wọn kúrò ní Éjíbítì di ìsin yìí Olúwa sì dáhùn pé Mo ti dárí jìn wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ Ṣùgbọ́n nítòótọ́ bí mo ti wà láàyè, gbogbo ayé yóò kún fún ògo Olúwa Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí òg mi àti wọn iṣẹ́ àmì ìyanu tí mo ṣe ní ilẹ̀ Éjíbítì àti nínú ihà ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí, Ọ̀kan nínú wọn kò níi rí ilẹ̀ náà tí mo ṣe ìlérí ní ìbúra láti fún baba ńlá wọn Kò sí ọ̀kan nínú àwọn tó kẹ́gàn mi tí yóò rí ilẹ̀ náà Ṣùgbọ́n nítorí pé Kélẹ́bù ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mi ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀ Níwọ̀n ìgbà tí àwọn ará Ámálékì àti àwọn ará Kénánì ń gbé ní àfonífojì, ẹ yípadà lọ́la kí ẹ sì dojú kọ ihà lọ́nà Òkun Pupa Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ìjọ ènìyàn búburú yìí yóò fi máa kùn sími Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kùn sí mi Sọ fún wọn, Bí Mo ti wà láàyè nítòótọ́ ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ wí létí mi ni èmi ó ṣe fún un yín Nínú ihà yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yín tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà Ọ̀kan nínú yín kò ní í dé ilẹ̀ tí mo búra láti fi ṣe ilẹ̀ yín, àyàfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè àti Jósúà ọmọ Núnì Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ yín tí ẹ wí pé wọn ó di ìjẹ, àwọn ni n ó mú dé bẹ̀ láti gbádùn ilẹ̀ tí ẹ kọ̀ sílẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, òkú yín yóò ṣubú ní ihà yìí Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín yóò sì máa rin kiri nínú ihà fun ogójì ọdún wọn ó máa jìyà nítorí àìnígbàgbọ́ yín, títí tí ọkàn gbogbo yín yóò fi ṣòfò tán ní ihà Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi Èmi, Olúwa , lo sọ bẹ́ẹ̀ Èmi ó sì ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ìjọ ènìyàn búburú yìí tí wọ́n kóra wọn jọ lòdì sí mi Nínú ihà yìí ni òpin yóò dé bá wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò kú sí Àwọn ọkùnrin tí Mósè rán láti yẹ ilẹ̀ wò, tí wọ́n sì mú àwọn ènìyàn kùn sí i nípa ìròyìn búburú tí wọ́n mú wá nípa ilẹ̀ náà Olúwa sì kọlu àwọn ọkùnrin tó mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀-àrùn sì pa wọ́n níwájú Olúwa Nínú gbogbo àwọn tó lọ yẹ ilẹ̀ náà wò, Jóṣúà ọmọ Núnì àti Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ló yè é Nígbà tí Mósè sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì sunkún gidigdidi Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n sì gòkè lọ sí ìlú orí òkè, wọ́n wí pé, Àwa ti ṣẹ̀, Àwa yóò lọ síbi tí Olúwa ṣèlérí fún wa Mósè sì dá wọn lóhùn pé, Kí ló dé tí ẹ fi ṣẹ̀ sí òfin Olúwa Èyí kò le yọrí sí rere! Ẹ má ṣe gòkè lọ nítorí pé Olúwa kò sí láàrin yín Ki á má baà lù yín bolẹ̀ níwájú àwọn ọ̀ta yín Nítorí pé àwọn ará Ámélékì àti àwọn ará Kénánì yóò kojú yín níbẹ̀ Nítorí pé Ẹ ti yà kúrò ní ọ̀nà Olúwa , Olúwa kò sì ní í wà pẹ̀lú yín Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, pẹ̀lú àìfarabalẹ̀ wọn, wọ́n gòkè lọ sórí òkè náà, láì jẹ́ pé àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa tàbí Mósè kúrò nínú ibùdó Àwọn ará Ámálékì àti àwọn ará Kénánì tó ń gbé lórí òkè sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n, wọ́n bá wọn jà, wọ́n sì lé wọn títí dé Hómà Àwọn Ọrẹ Àfikún Olúwa sọ fún Mósè pé Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi ó fún yin gẹ́gẹ́ bí ibùgbé tí ẹ sì mú ọrẹ àfinásun wá, yálà nínú ọ̀wọ́ ẹran gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa , bóyá ọrẹ sísun tàbí ẹbọ sísun, láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí ọrẹ àtinúwá, nígbà náà ni kí ẹni tí ó bá mú ọrẹ rẹ̀ wá, yóò tún mú ẹbọ ohun jíjẹ ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúná pẹ̀lú ìdásímẹ́rin òṣùwọ̀n òróró wá ṣíwájú Olúwa Pẹ̀lú ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan yálà fún ọrẹ tabí ẹbọ sísun ni, kí ẹ pèsè ìdá sí mẹ́rin òṣùwọ̀n wáìnì gẹ́gẹ́ bí ohun mímu  Fún àgbò kan ni kí ẹ pèsè ọrẹ ohun jíjẹ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdá kan nínú mẹ́ta òṣùwọ̀n òróró pò Àti ìdá kan nínú mẹ́ta òṣùwọ̀n wáìnì fún ọrẹ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa  Nígbà tí ẹ bá sì pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ọrẹ tàbí ẹbọ sísun, láti fi san ẹ̀jẹ́ tàbí fún ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa , Ẹni náà yóò mú ọ̀dọ́ akọ màlúù náà wá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, ìdá sí mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúná tí a fi ìdajì òṣùwọ̀n òróro pò Kí ó tún mú ìdajì òsùwọ̀n wáìnì wá fún ọrẹ ohun mímu Yóò jẹ́ ọrẹ àfinásun, àní òórùn dídùn sí Olúwa Báyìí ni kí ẹ se pèṣè ọ̀dọ́ akọ màlúù tàbí àgbò, ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí ọmọ ewúrẹ́ Ẹ se bẹ́ẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, iyekíye tí ẹ̀yin ì bá à pèsè  Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ yín ni kí ó máa se àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí ó bá mú ọrẹ àfinásun gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn wá fún Olúwa Bí àléjò kan bá ń gbé láàrin yín ní gbogbo ìran yín, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ mú ọrẹ àfinásun bí òórùn dídùn wá fún Olúwa , gbogbo bí ẹ bá ṣe ń ṣe náà ni kí ó ṣe Gbogbo ìjọ ènìyàn gbọdọ̀ ní òfin kan náà fún ọmọ bíbí ilẹ̀ yín àti fún àwọn àlejò tó ń gbé láàrin yín, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún àwọn ìran tó ń bọ̀ Ẹ̀yin àti àlejò tó ń gbé láàrin yín sì jẹ́ bákan náà níwájú Olúwa Òfin kan àti ìlànà kan ni yóò wà fún yín àti fún àwọn àlejò tí ń gbé láàrin yín   Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún àwọn ọmọ Ísirẹ́lì pé, Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mo ń mú yín lọ Tí ẹ sì jẹ oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ mú nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè wá fún Olúwa Ẹ mú àkàrà wá nínú àkọ́so oúnjẹ yín wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè sí Olúwa , ọrẹ láti inú ilẹ̀ ìpakà yín Nínú àkọ́so oúnjẹ yín ni kí ẹ ti máa mú ọrẹ ìgbésókè yìí fún Olúwa  Bí ẹ bá kùnà láìròtẹ́lẹ̀ láti pa àwọn òfin tí Olúwa fún Mósè mọ́ Èyí ni gbogbo òfin tí Olúwa fún yín láti ẹnu Mósè láti ọjọ́ tí Olúwa ti fún yín àti títí dé ìran tó ń bọ̀ Bí ẹ̀ṣẹ̀ bá wáyé láìròtẹ́lẹ̀ láì jẹ́ pé ìjọ ènìyàn mọ̀ sí i, nígbà náà ni kí gbogbo ìjọ ènìyàn mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan wá fún ẹbọ sísun bí òórùn dídùn sí Olúwa , pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà, pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Àlùfáà yóò sì se ètùtù, fun gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì, a ó sì dárí jìn wọ́n, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti mú ọrẹ àfinásun wá fún Olúwa nítori ẹ̀sẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ A ó dárí ji gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì àti àwọn àlejò tí ń gbé ní àárin wọn nítorí pé ní àìròtẹ́lẹ̀ ni wọ́n sẹ ẹ̀ṣẹ̀ náà  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé ẹnìkan ló sẹ̀ ní àìròtẹ́lẹ̀, kí ó mú abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Àlùfáà yóò ṣe ètùtù níwájú Olúwa fún ẹni tó ṣẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, tí wọ́n bá ṣe ètùtù fún un, a ó sì dárí jì í Òfin kan náà ló wà fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, yálà ọmọ bíbí ilẹ̀ yín tàbí àlejò tí ń gbé láàrin yín  Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá mọ̀-ọ́n-mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ yálà ó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ yín tàbí àlejò, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Olúwa , a ó sì gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀ Nítorí pé ẹni náà ti kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa ó sì ti rú òfin rẹ̀, a gbọdọ̀ gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí rẹ̀   Nígbà tí àwọn ọmọ Ísirẹ́lì wà nínú ihà, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣa igi ní ọjọ́ Ísínmì Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣa igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mósè àti Árónì àti ṣíwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Wọ́n fi sí ìpamọ́ nítorí pé ohun tí wọn ó ṣe fún un kò tí ì yé wọn Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Kíkú ni ọkùnrín náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sọ ọ́ lókúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó Wọ́n mú un jáde sí ẹ̀yìn ibùdó, gbogbo ìjọ ènìyàn sì sọ ọ́ lókúta pa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Olúwa sọ fún Mósè pé, Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sọ fún wọn pé Títí dé àwọn ìran tó ń bọ̀ ni kí wọn máa ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn, kí wọn sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ búlúù sí wajawaja kọ̀ọ̀kan Wajawaja yìí ni ẹ sì máa wò láti lè mú yín rántí gbogbo òfin Olúwa , kí ẹ bá à lè ṣe wọ́n, kí ẹ sì má bá à ṣe àgbérè nípa títẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àti ojú yín Nígbà náà ni ẹ ó gbọ́ran láti pa gbogbo òfin mi mọ́, ẹ ó sì jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run yín Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti Éjíbítì láti jẹ́ Ọlọ́run yín Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín   Ìṣọ̀tẹ̀ Kórà, Dátanì àti Ábírámù Kórà ọmọ Íṣárì, ọmọ Kóhátì, ọmọ Léfì àwọn ọmọ Rúbẹ́nì Dátanì àti Ábírámù, àwọn ọmọ Élíábù, àti Ónù ọmọ Pélétì mú ènìyàn mọ́ra Wọ́n sì dìde sí Mósè, Pẹ̀lú àádọ́tàlénígba ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gbajúmọ̀ nínú ìgbìmọ̀ ìlú Wọ́n kó ara wọn jọ láti tako Mósè àti Árónì, wọ́n sọ fún wọn pé, Ẹ ti kọjá ààyè yín, ó tó gẹ́ ẹ́! Mímọ́ ni gbogbo ènìyàn, kò sí ẹni tí kò mọ́ láàrin wọn, Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn, nítorí kí wá ni ẹ̀yin ṣe gbé ara yín ga ju ìjọ ènìyàn Olúwa lọ Nígbà tí Mósè gbọ́ èyí, ó dojú bolẹ̀, Ó sì sọ fún Kórà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, Ní ọ̀la ni Olúwa yóò fi ẹni tí í ṣe tirẹ̀ àti ẹni tó mọ́ hàn, yóò sì mú kí ẹni náà súnmọ́ òun Ẹni tí ó bá yàn ni yóò mú kí ó súnmọ́ òun Kí Kórà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe èyí, Ẹ mú àwo tùràrí Kí ẹ sì fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀ lọ́la níwájú Olúwa , yóò si se, ọkùnrin tí Olúwa bá yàn oun ni Ẹ̀yin ọmọ Léfì, ẹ ti kọjá ààyè yín! Mósè sì tún sọ fún Kórà pé, Ẹ gbọ́ báyìí o, ẹ̀yin ọmọ Léfì! Kò ha tọ́ fún yín pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti yà yín sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù, tó sì mú yín súnmọ́ ara rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ Olúwa àti láti dúró ṣiṣẹ́ ìsìn níwájú àwọn ènìyàn Ó ti mú àwọn ènìyàn yín tó jẹ́ ọmọ Léfì súnmọ́ ara rẹ̀, ṣùgbọ́n báyìí ẹ tún ń wá ọnà láti ṣiṣẹ́ àlùfáà Olúwa ni ìwọ àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ takò Ta a ni Árónì jẹ́ tí ẹ̀yin ó fi kùn sí i Mósè sì ránṣẹ́ sí Dátanì àti Ábírámù àwọn ọmọ Élíábù Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé Àwa kò ní í wá! Kò ha tó gẹ́ ẹ́ pé o ti mú wa jáde láti ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin láti pa wá sínú ihà yìí O tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di Olúwa lé wa lórí bí Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ìwọ kò sì tí ì mú wa dé ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì pín ilẹ̀ ìní wa fún wa Ìwọ ha fẹ́ sọ wá di ẹrú bí Rárá o, àwa kò ní wá! Nígbà náà ni Mósè bínú gidigidi, ó sì sọ fún Olúwa pé, Má ṣe gba ọrẹ wọn, èmi kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì pa ẹnikẹ́ni nínú wọn lára! Mósè sọ fún Kórà pé, Ìwọ àti ọmọ lẹ́yìn rẹ gbọdọ̀ fara hàn níwájú Olúwa lọ́la—gbogbo yín, ìwọ, àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ àti Árónì Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín mú àwo tùràrí, kí ó sì fi tùràrí sínú rẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ àádọ́tàlénígba àwo tùràrí kí ẹ sì ko wá ṣíwájú Olúwa Ìwọ àti Árónì yóò mú àwo tùràrí wá pẹ̀lú Nígbà náà ni oníkálukú wọn mú àwo tùràrí, wọ́n fi iná àti tùràrí sí i nínú, wọ́n sì dúró sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé, àwọn pẹ̀lú Mósè àti Árónì Nígbà tí Kórà kó gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé, ògo Olúwa sì farahan gbogbo ìjọ ènìyàn Olúwa sì sọ fún Mósè àti Árónì pé, Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọ̀nyí, kí ń ba à le pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà Ṣùgbọ́n Mósè àti Árónì dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mi gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣẹ̀ Olúwa tún sọ fún Mósè pé, Sọ fún ìjọ ènìyàn pé, Kí wọ́n jìnnà sí àgọ́ Kórà, Dátanì àti Ábírámù   Mósè sì dìde lọ bá Dátanì àti Ábírámù àwọn olórí Ísírẹ́lì sì tẹ̀lé Ó sì kìlọ̀ fún ìjọ ènìyàn pé, Ẹ kúrò ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú yìí! Ẹ má ṣe fọwọ́ kan ohun kan tí í ṣe tiwọn kí ẹ má ba à parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn Àwọn ènìyàn sì sún kúrò ní àgọ́ Kórà, Dátanì àti Ábírámù Dátanì àti Ábírámù jáde, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ wọn sì dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn Nígbà náà ni Mósè wí pé, Báyìí ni ẹ ó ṣe mọ̀ pé Olúwa ló rán mi láti ṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí àti pé kì í ṣe ìfẹ́ inú mi ni àwọn ohun tí mò ń ṣe Bí àwọn ènìyàn yìí bá kú bí gbogbo ènìyàn ti ń kú, bí ìrírí wọn kò bá sì yàtọ̀ sí ti àwọn ènìyàn yóòkù, a jẹ́ pé kì í ṣe Olúwa ló rán mi Ṣùgbọ́n bí Olúwa bá ṣe ohun túntún, tí ilẹ̀ sì la ẹnu, tó gbé wọn mì, àwọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní, tí wọ́n sì wọ inú ibojì wọn lọ láàyè, nígbà náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn yìí ti kẹ́gàn Olúwa Bí ó sì ṣe parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ilẹ̀ pín sí méjì nísàlẹ̀ wọn, ilẹ̀ sì lanu ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ará ilé wọn àti àwọn ènìyàn Kórà àti gbogbo ohun tí wọ́n ní Gbogbo wọn sì sọ̀kalẹ̀ sínú ibojì wọn láàyè pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n ní, ilẹ̀ sì padé mọ́ wọn, wọ́n sì ṣègbé kúrò láàrin ìjọ ènìyàn Nígbà tí àwọn yóòkù gbọ́ igbe wọn, wọ́n sálọ, wọ́n wí pé, Ilẹ̀ yóò gbé àwa náà mì pẹ̀lú Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì run àádọ́tàlénígba ọkùnrin tí wọ́n mú tùràrí wá Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún Élíásárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà, pé kí ó mú àwọn àwo tùràrí jáde kúrò nínú iná nítorí pé wọ́n jẹ́ mímọ́, kí ó sì tan iná náà káàkiri síbi tó jìnnà Èyí ni àwo tùràrí àwọn tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn Kí ẹ gún àwo tùràrí yìí, kí ẹ sì fi ṣe ìbòrí fún pẹpẹ, wọ́n jẹ́ mímọ́ nítorí pé wọ́n ti mú wọn wá ṣíwájú Olúwa Kí wọ́n jẹ́ àmì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Élíásárì tí í ṣe àlùfáà sì kó gbogbo àwo tùràrí tí àwọn tí ó jóná mú wa, ó gún wọn pọ̀, ó fi ṣe ìbòrí fún pẹpẹ, Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ṣe sọ láti ẹnu Mósè Èyí yóò jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ẹlòmíràn yàtọ̀ sí irú ọmọ Árónì kò gbọdọ̀ jó tùràrí níwájú Olúwa , ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò dàbí Kórà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ Ní ọjọ́ kejì gbogbo ìjọ ènìyàn kùn sí Mósè àti Árónì pé, Ẹ ti pa àwọn ènìyàn Olúwa Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn péjọ lòdì sí Mósè àti Árónì, níwájú àgọ́ ìpàdé, lójijì ni ìkúùkù bolẹ̀, ògo Olúwa sì fara hàn Nígbà náà ni Mósè àti Árónì lọ ṣíwájú àgọ́ ìpàdé, Olúwa sì sọ fún Mósè pé, Yàgò kúrò láàrin ìjọ ènìyàn yìí, kí ń ba le run wọ́n ní ìṣẹ́jú kan Wọ́n sì dojú bolẹ̀ Mósè sì sọ fún Árónì pé, Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárin ìjọ ènìyàn láti ṣètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú Olúwa ti jáde, àjàkálẹ̀-àrùn sì ti bẹ̀rẹ̀ Árónì ṣe bí Mósè ti wí, ó sáré lọ sí àárin àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-àrùn ti bẹ̀rẹ̀ láàrin wọn, ṣùgbọ́n Árónì fín tùràrí, ó sì ṣe ètùtù fún wọn Ó dúró láàrin àwọn alààyè àti òkú, àjàkálẹ̀-àrùn náà sì dúró Ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-àrùn ti pa ẹgbàá méje ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ènìyàn ní àfikún sí àwọn tí ó kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ Kórà Árónì padà tọ Mósè lọ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpade nítorí pé àjàkálẹ̀-àrùn náà ti dúró Ọ̀pá Árónì Rúwé Olúwa sì sọ fún Mósè pé Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí o sì gba ọ̀pá méjìlá lọ́wọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ olórí ìdílé ẹ̀yà ìran wọn, kọ orúkọ ènìyàn kọ̀ọ̀kan sí ara ọ̀pá rẹ̀ Lórí ọ̀pá Léfì kọ orúkọ Árónì, nítórí ọ̀pá kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà fún olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan tí yóò jẹ́ orí fún ẹ̀yà ìran kọ̀ọ̀kan Kó wọn sí Àgọ́ Ìpàdé níwájú Ẹ̀rí níbi tí èmi ti ń pàdé yín Ọ̀pá tí ó bá yí jẹ́ ti ẹni tí èmi bá yàn yóò rú wé, èmi yóò sì dá kíkùn gbogbo ìgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí yín dúró Nígbà náà Mósè bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, àwọn olórí wọn sì fún un ní ọ̀pá méjìlá, ọ̀pá kan fún olórí kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà ìran wọn, ọ̀pá Árónì sì wà lára àwọn ọ̀pá náà Mósè sì fi ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú Olúwa nínú àgọ́ ẹ̀rí Ó sì se ní ọjọ́ kéjì Mósè wọ inú àgọ́ ẹ̀rí lọ, ó sì rí ọ̀pá Árónì, tí ó dúró fún ẹ̀yà Léfì, kì í ṣe wí pé ó hù nìkan Ṣùgbọ́n ó ruwé, ó yọ ìtànná, ó sì so èso jíjẹ Nígbà náà ni Mósè kó gbogbo àwọn ọ̀pá jáde láti iwájú Olúwa wá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Wọ́n wò wọ́n, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì mú ọ̀pá tirẹ̀ Olúwa sọ fún Mósè pé, Mú ọ̀pá Árónì padà wá ṣíwájú Ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àmìn fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má baà kú Mósè sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa a láṣẹ fún un Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ fún Mósè pé, Àwa yóò kú! A ti sọnù, gbogbo wa ti sọnù! Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ tabánákù Olúwa yóò kú Ṣé gbogbo wa ni yóò kú Iṣẹ́ Àwọn Àlùfáà Àti Àwọn Ọmọ Léfì Olúwa sọ fún Árónì pé, Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé bàbá rẹ ni yóò ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá fún ilé tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run, àti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóò máa ru ẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà yín Kí o sì mú àwọn ènìyàn rẹ ará Léfì láti ẹ̀yà ìran rẹ láti dàpọ̀ mọ́ ìwọ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ níwájú Àgọ́ Ẹ̀rí Àwọn ni óyẹ láti dúró fún ọ àti láti ṣe gbogbo iṣẹ́ ti Àgọ́, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi tí a ti ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ tí a sì yà sí mímọ́ tàbí ibi pẹpẹ, tàbí gbogbo wọn àti ìwọ ló máa kú Ó yẹ kí wọ́n darapọ̀ mọ́ ọ láti jẹ ìyà iṣẹ́ fún àìtọ́jú ibi ti Àgọ́ Ìpàdé àti gbogbo iṣẹ́ tí ó wà ní ibi àgọ́, àti wí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ẹ̀gbẹ́ ibi tí o wà Kí o sì mójú tó iṣẹ́ ibi mímọ́ àti iṣẹ́ ibi pẹpẹ, kí ìbínú má ba wá sí orí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ Èmi fúnra mi ti yan àwọn arákùnrin rẹ tí í ṣe ọmọ Léfì kún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù, wọn jẹ́ ẹ̀bùn fún ọ, èyí ni a fún Olúwa láti ṣe iṣẹ́ tí ó wà ní àgọ́ ìpàdé Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ni yóò mójú tó iṣẹ́ àlùfáà yín fún gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ ibi pẹpẹ àti ti ẹ̀yin aṣọ títa, ẹ ó sì máa ṣiṣẹ́ ibi pẹpẹ àti nínú aṣọ tí a ta Mo fún ọ ní iṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn Ṣùgbọ́n àlejò tí ó bá sún mọ́ tòòsí ibi ìyà sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni a ó pa Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Árónì pé, Èmi fúnra mi ti fi ọ́ ṣọ́ ìdi gbogbo ẹbọ tí a bá mú wá fún gbogbo ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fún mi, mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe Ìwọ ni kí o ni ìpín ọrẹ mímọ́ jùlọ tí a mú kúrò ní ibi iná, nínú gbogbo ọrẹ tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ mímọ́ jùlọ, yálà ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ẹbọ ẹ̀bi, ìpin wọ̀nyí jẹ́ ti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ Ẹ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ jùlọ, gbogbo ọkùnrin ni ó gbọdọ̀ jẹ ẹ́ Ó gbọdọ̀ kà á sí mímọ́, Èyí tún jẹ́ tìrẹ pẹ̀lú ohunkóhun tí a bá yà sọ́tọ̀ lára ẹ̀bùn ọrẹ fífì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Mó fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ipin tí yóò máa ṣe déédé nínú ìdílé rẹ, tí o bá wà ní mímọ́ ni o le jẹ ẹ́ Mo fún ọ ní gbogbo òróró tí ó dára jùlọ àti gbogbo ọtí titun dáradára jùlọ àti ọkà tí wọ́n mú wá fún Olúwa ní àkọ́so ohun ọ̀gbìn wọn tí wọ́n kórè Gbogbo àkọ́so nǹkan ilẹ̀ wọ́n tí wọn mú wá fún Olúwa yóò jẹ́ tìrẹ, Ẹnikẹ́ni nínú ìdílé rẹ, àwọn tí ó jẹ́ mímọ́ nínú ìdílé rẹ lè jẹ ẹ́ Gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ní Ísírẹ́lì jẹ́ tìrẹ Gbogbo àkọ́bí nínú gbogbo ohun alààyè tí wọ́n mú wá fún Olúwa , ìbá à jẹ́ ti ènìyàn tàbí ti ẹranko jẹ́ tìrẹ ṣùgbọ́n o gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin padà àti àkọ́bí àwọn ẹranko aláìmọ́ Nígbà tí wọ́n bá pé oṣù kan, o gbọdọ̀ rà wọ́n padà ní iye owó ìràpadà tí í ṣe ṣékélì márùn ún fàdákà, gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ tí ó wọn ìwọn ogún gérà Ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ra àwọn àkọ́bí ọmọ màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́ wọ́n jẹ́ mímọ́ Wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ kí o sì sun ọ̀rá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfinásun, ẹbọ òórùn dídùn sí Olúwa Ẹran wọn gbọdọ̀ jẹ́ tìrẹ, gẹ́gẹ́ bí ìgẹ̀ ọrẹ ẹbọ fífì àti itan ọ̀tún ṣe jẹ́ tìrẹ Ohunkóhun tí a bá ti yà sọ́tọ̀ nínú ọrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n mú wá fún Olúwa ni mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe déédé Ó jẹ́ májẹ̀mú iyọ̀ láéláé níwájú Olúwa fún ìwọ àti ọmọ rẹ Olúwa sọ fún Árónì pé, O kò ní ní ogún nínú ilẹ̀ wọn bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ní ní ìpín láàrin wọn, Èmi ni ìpín àti ogún rẹ láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Mó ti fún àwọn ọmọ Léfì ní gbogbo ìdámẹ́wàá ní Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ogún fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi àgọ́ ìpàdé Láti ìsinsinyìí àwọn ọmọ Ísírẹ́li, kò gbọdọ̀ súnmọ́ àgọ́ ìpàdé, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò jẹ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn á sì kú Àwọn ọmọ Léfì ní ó gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí wọ́n bá kúrò láti ṣe é Èyí ni ìlànà láéláé fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀ Wọn kò ní gba ogún kankan láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí ogún wọn, ìdá kan nínú ìdá mẹ́wàá tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pèsè gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa Èyí ni mo wí nípa wọn Wọn kò ní gba ogún kankan láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún àwọn ọmọ Léfì kí o sì wí fún wọn pé Nígbà tí ìdámẹ́wàá bá ń wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ O gbọdọ̀ mú ìdámẹ́wàá lára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Olúwa A ó ka ọrẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkà irúgbìn láti ilé ìpakà tàbí wáìnì láti fún wa Báyìí ni ìwọ gan an náà yóò mú ọrẹ wa fún Olúwa láti ara ìdámẹ́wàá tí ìwọ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Láti ara ìdámẹ́wá ó gbọdọ̀ mú ọrẹ Olúwa fún Árónì àlùfáà Ìwọ gbọdọ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí ìpín Olúwa èyí tí ó dára jùlọ àti tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ lára gbogbo nǹkan tí wọ́n mú wá fún ọ Sọ fún àwọn ọmọ pé Nígbà tí ẹ̀yin bá mú ìpín tí ó dára jù wá, a ó kà á sí fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí ìkórè láti ilẹ̀ ìpakà tàbí ìfúntí yín Ìwọ àti àwọn ìdílé rẹ̀ le jẹ èyí tí ó kù ní ibikíbi gbogbo Nítorí pé ó jẹ́ ọrẹ fún iṣẹ́ rẹ níbi àgọ́ ìpàdé Nípa ṣíṣe ìgbékalẹ̀ ìpín tí ó dára jùlọ o kò ní jẹ̀bi lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ kò sì ní ba ọrẹ mímọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́, ìwọ kì yóò sì kú   Omi Ìwẹ̀nùmọ́ Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé Èyí ni ohun tí òfin Olúwa pa láṣẹ béèrè lọ́wọ́ yín Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọn mú ẹgbọrọ ọ̀dọ́ màlúù pupa tí kò lábùkù tàbí àbàwọ́n, tí kò sì tí ì ru ẹrù rí Ẹ mú fún Élíásárì àlùfáà, yóò sì mu jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó kí ó sì pa á ní ojú rẹ Nígbà náà ni Élíásárì àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí ìka ọwọ́ rẹ̀ yóò sì wọn lẹ́ẹ̀méje ní ọ̀kánkán iwájú àgọ́ ìpàdé Ní ojú rẹ̀ ni àlùfáà yóò ti sun ọ̀dọ́ abo màlúù yìí awọ ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹran ara àti ìgbẹ́ rẹ̀ Àlùfáà yóò mú igi òpépé, hísópù àti òwú òdòdó yóò sì jù wọ́n sí àárin ọ̀dọ́ abo màlúù tí a ń sun Lẹ́yìn náà, Àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ̀yìn náà ó lè wá sínú àgọ́ Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ Ẹni tí ó sun ún náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pèlú omi, òun náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títi di ìrọ̀lẹ́ Ẹni tó wà ní mímọ́ ni yóò kó eérù ọ̀dọ́ màlúù náà lọ sí ibi tí a yà sí mímọ́ lẹ́yìn ibùdó Kí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì kó o pamọ́ fún lílò fún omi ìwẹ̀nùmọ́ Ó jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Ọkùnrin tí ó kó eérú ọ̀dọ́ abo màlúù náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti fún àwọn àlejò tí ó ń gbé láàrin wọn Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́kan òkú ẹnikẹ́ni, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje Ó gbọ̀dọ̀ wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi ní ọjọ́ kẹ́ta àti ní ọjọ́ kéje nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́ Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé kò wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹ́ta àti ní ọjọ́ kéje yóò jẹ́ aláìmọ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnìkan tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ó ba àgọ́ Olúwa jẹ́ A ó ké irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Nítorí pé a kò tí ì wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ lé e lórí, ó jẹ́ aláìmọ́, àìmọ́ rẹ̀ sì wà lára rẹ̀ Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ bí ènìyàn bá kú nínú àgọ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú àgọ́ àti ẹni tí ó wà nínú àgọ́ yóò di aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, Gbogbo ohun èlò tí a kò bá fi ómẹ́rì dé ni yóò jẹ́ aláìmọ́ Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ìta tí ó sì fi ọwọ́ kan ẹni tí a fi idà pa tàbí ẹni tí ó kú ikú àtọ̀runwá, tàbí bí ẹ̀nìkan bá fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí iṣà òkú, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje Fún aláìmọ́ ènìyàn, mú eérú díẹ̀ lára eérú ọrẹ ìwẹ̀nùmọ́ sínú ìgò, kí o sì da omi tó ń sàn lée lórí Nígbà náà, ọkùnrin tí a yà sí mímọ́ yóò mú hísópù díẹ̀ yóò rì í sínú omi yóò sì fi wọ́n àgọ́ àti gbogbo ohun èlò tí a se lọ́ṣọ̀ọ́ àti àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀ O gbọdọ̀ tún fi wọ́n ẹnikẹ́ni tí ó fí ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí iṣà òkú, tàbí ẹni tí ó kú ikú ara rẹ̀, tàbí ẹni tí ó kú ikú àti ọ̀run wá Ọkùnrin tí ó mọ́ ni kí ó bu omi wọ́n àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ọjọ́ kẹ́ta àti ọjọ́ kéje, ní ọjọ́ kéje ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ mọ́, Ẹni tí a wẹ̀ mọ́ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà yóò mọ́ Ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ kò bá wẹ ara rẹ̀ mọ́, a gbọdọ̀ gé e kúrò nínú ìjọ ènìyàn, nítorí wí pé ó ti ba àgọ́ Olúwa jẹ́ A kò tíì fi omi ìwẹ̀nùmọ́sí ara rẹ̀, ó sì jẹ́ aláìmọ́ Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún wọn Ọkùnrin tí ó wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ àti ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan omi ìwẹ̀nùmọ́ yóò di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ Gbogbo ohun tí ẹni tí ó jẹ́ aláìmọ́ bá fi ọwọ́ kàn yóò di àìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ Ètò Ibùdó Ẹ̀yà Kọ̀ọ̀kan Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa Àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àṣíá ìdílé wọn Ní ìlà oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn ni kí ìpín ti Júdà pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn Olórí Júdà ni Náṣónì ọmọ Ámínádábù Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta Ẹ̀yà Ísákárì ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn Olórí Ísákárì ni Nìtaníẹ́lì ọmọ Súárì Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlọ́gbọ̀n ó lé irínwó Ẹ̀yà Sébúlúnì ni yóò tẹ̀lé e Olórí Sébúlónì ni Élíábù ọmọ Hélónì Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n-ó-lé-egbéje Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Júdà, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́taléláàdọ́rin ó lé irínwó Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú Ní ìhà gúsù ni ìpín ti Rúbẹ́nì pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn Olórí Rúbẹ́nì ni Elisúrì ọmọ Ṣedúérì Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́talélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Ẹ̀yà Símónì ni yóò pa ibùdó tẹ́lé wọn Olórí Símónì ni Ṣélúmíélì ọmọ Surisadáì Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje Ẹ̀yà Gáádì ló tẹ̀lé wọn Olórí Gáádì ni Eliásáfì ọmọ Déúélì Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́ta Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Rúbẹ́nì, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rún ó lé àádọ́tàlélégbéje Àwọn ni yóò jáde sìkéjì Nígbà náà ni àwọn ọmọ Léfì Àti Àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀ṣíwájú láàrin ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀ṣíwájú ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láàyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀ Ní ìhà ìlà oòrùn ni ìpín Éfúráímù yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ́págun rẹ̀ Olórí Éfúráímù ni Élíṣámà ọmọ Ámíhúdì Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Ẹ̀yà Mánásè ni yóò tẹ̀lé wọn Olórí Mánásè ni Gàmálíélì ọmọ Pedasúrì Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́rìndínlógún-ó-lé-igba Ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni yóò tẹ̀ lé e Olórí Bẹ́ńjámínì ni Ábídánì ọmọ Gídíónì Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́tadínlógún ó lé egbéje Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Éfúráímù, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnléláàdọ́ta-ó-lé-ọgọ́rùn-ún Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta Ní ìhà àríwá, ni ìpín Dánì yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn Olóri Dánì ni Áyésérì ọmọ Ámíṣádáyì Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin Ẹ̀yà Ásérì ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn Olórí Ásérì ni Págíélì ọmọ Ókíránì Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ Ẹ̀yà Náfítanì ni yóò kàn lẹ́yìn wọn Olórí Náfítanì ni Áhírà ọmọ Énánì Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún-ó-lé-egbéje Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dánì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gọ̀rún-ó-lé-ẹgbẹ̀jọ Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́-ó-lé-egbéjìdínlógún-dín àádọ́ta Ṣùgbọ́n a kò ka àwọn ọmọ Léfì papọ̀ mọ́ àwọn Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì se gbogbo ohun tí Olúwa pa láṣẹ fún Mósè, báyìí ni wọ́n ṣe pa ibùdó lábẹ́ ọ̀págun wọn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n ṣe jáde, oníkálùkù pẹ̀lú ẹbí àti ìdílé rẹ̀ Omi Láti Inú Àpáta Ní osù kìn-ní-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Ísírẹ́lì gúnlẹ̀ sí pápá Sínì, wọ́n sì dúró ní Kádésì Níbẹ̀ ni Míríámù kú, wọ́n sì sin ín Nísinyìí kò sì sí omi fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kóra wọn jọ lòdì sí Mósè àti Árónì, Wọ́n bá Mósè jà wọ́n sì wí pé, Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arakùnrin ti kú níwájú Olúwa ! Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn Olúwa wá sí ihà yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa báà kú síbí Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Éjíbítì wá sí ibi búburú yìí Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èṣo àjàrà tàbí pamonganati Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhín-ín! Mósè àti Árónì kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahàn wọ́n Olúwa sọ fún Mósè pé, Mú ọ̀pá, náà kí o sì pe ìjọ àwọn ènìyàn jọ, ìwọ àti Árónì arákùnrin rẹ, kí ẹ sọ̀rọ̀ sí àpáta náà ní ójú wọn, yóò sì tú omi rẹ̀ jáde ìwọ ó sì fún ìjọ àti ẹran wọn mu Báyìí ni Mósè mú ọ̀pá láti iwájú Olúwa wá, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ fún un Òun àti Árónì pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mósè sì sọ fún wọn, Ẹ gbọ́, ẹ̀yín ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí Nígbà náà ni Mósè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé, Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn Èyí ni omi ti Méríbà, níbi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti bá Olúwa jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrin wọn Mósè sì ránṣẹ́ láti Kádésì sí ọba Édómù, wí pé Èyí ni nǹkan tí arákùnrin rẹ Ísírẹ́lì sọ Ìwọ ti mọ̀ nípa gbogbo ìnira, tí ó wá sí orí wa Àwọn bàbá ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Éjíbítì, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún Àwọn ará Éjíbítì ni wá lára àti àwọn bàbá wa, ṣùgbọ́n nígbà tí a sunkún sí Olúwa , ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán ańgẹ́lì kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Éjíbítì Báyìí àwa wà ní Kádésì, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀ èdè rẹ kọjá, Àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kàǹga A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ Ṣùgbọ́n Édómù dáhùn pé Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun síyín a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dáhùn pé A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀ A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkankan mìíràn tí a fẹ́ ṣe Wọ́n tún dáhùn wí pé Ẹ kò lè kọjá Nígbà náà ni Édómù jáde wá láti kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àti alágbára ọmọ ogun Nígbà tí Édómù sì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí wọn kọjá ní ilẹ̀ wọn, Ísírẹ́lì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn Gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì jáde láti Kádésì wọ́n sì wá sí orí òkè Hórì Ní orí òkè Hórì, ní ẹ̀gbẹ́ ààlà Édómù Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé, Árónì yóò kú Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Méríbà Mú Árónì àti ọmọ rẹ̀ Élíásárì lọ sí orí òkè Hórì Bọ́ aṣọ Árónì kí o sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Élíásárì, nítorí pé Árónì yóò kú ṣíbẹ̀ Mósè sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa láṣẹ Wọ́n lọ sí orí òkè Hórì ní ojú gbogbo ìjọ ènìyàn Mósè bọ́ aṣọ Árónì ó sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Élíásárì, Árónì sì kú sí orí òkè Nígbà náà Mósè àti Élíásárì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbọ́ pé Árónì ti kú, gbogbo ilé Ísírẹ́lì ṣe ìdárò rẹ̀ fún ọgbọ̀n ọjọ́ A Pa Ìlú Árádì Run Nígbà tí ọba Árádì ará Kénánì, tí ń gbé ní Gúúsù gbọ́ wí pé Ísírẹ́lì ń bọ̀ wá ní ojú ọ̀nà Átarímù, ó bá Ísírẹ́lì jà ó sì fi agbára mú díẹ̀ lára wọn Nígbà náà ni Ísírẹ́lì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa pé Bí o bá lè fi àwọn ènìyàn yìí lé wa lọ́wọ́, gbogbo ìlú wọn ni a ó pa run Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì fi àwọn ará Kénánì lé wọn lọ́wọ́ Wọ́n pa wọ́n run pátapáta torí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ ní Hómà Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hórì lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Édómù Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Olúwa àti Mósè, wọ́n wí pé, Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Éjíbítì kí a ba le wá kú sí ihà yìí Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kóríra oúnjẹ tí kò dára yìí! Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárin wọn wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kú Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mósè wọn wí pé, A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí a sọ̀rọ̀ òdì sí Olúwa àti sí ìwọ pẹ̀lú Gba àdúrà pé kí Olúwa mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa Nígbà náà ni Mósè gbàdúrà fún àwọn ènìyàn Olúwa sọ fún Mósè pé, Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè Nígbà náà ni Mósè sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ṣíwájú wọ́n sì péjọ sí Óbótì Wọ́n gbéra ní Óbótì wọ́n sì pa ibùdó sí Iye-àbárímù, ní ihà tí ó kọjú sí Móábù ní ìdojúkọ ìlà oòrùn Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gbéra wọ́n sì pa ibùdó ní àfonífojì Sérédì Wọ́n gbéra kúrò níbẹ̀ wọ́n sì pa ibùdó sí ẹ̀bá ọ̀nà Ánónì, tí ó wà ní Ìfà-gùn ihà tó kángun sí ibi tí ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámórì wa Ánónì jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Móábù, láàrin Móábù àti Ámórì Ìdí nì yìí tí ìwé ogun Olúwa ṣe wí pé …Wáhébù ní Súpà, òkun pupa àti ní odò Ánónì àti ní isà odò tí ó darí sí ibùjókòó Árí tí ó sì fara ti ìpìnlẹ̀ Móábù Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Béérì, èyí ni kànga tí Olúwa sọ fún Mósè, Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi Nígbà náà ni Ísírẹ́lì kọ orin yìí pé Sun jáde, ìwọ kànga! Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀, Nípa kanga tí àwọn ọmọ aládé gbẹ́, nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ẹ tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́ Nígbà náà wọ́n kúrò láti ihà lọ sí Mátanà, láti Mátanà lọ sí Náhálíẹ́lì, láti Náhálíẹ́lì lọ sí Bámótì, àti láti Bámótì lọ sí àfonífojì ní Móábù níbi tí òkè Písígà, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí ihà Ísírẹ́lì rán oníṣẹ́ láti sọ fún Síhónì ọba àwọn ará Ámórì wí pé Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀ èdè rẹ A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà tàbí mu omi láti inú kànga A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá Ṣùgbọ́n Síhónì kò ní jẹ́ kí àwọn Ísírẹ́lì kọjá ní ilẹ̀ wọn Ó pe àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì wọ́de ogun lọ sí ihà nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Nígbà tí ó dé Jánásì, ó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà Àmọ́ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Ánónì lọ dé Jábókù, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ámónì, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ìlú Ámórì wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Hésíbónì, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká Hésíbónì ni ìlú Ṣíhónì ọba àwọn ará Ámórì, ẹni tí ó bá ọba ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Ánónì Ìdí nì yí tí akọrin sọ wí pé Wá sí Hésíbónì kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́ jẹ́ kí ìlú Ṣíhónì padà bọ̀ sípò Iná jáde láti Hésíbónì, ọ̀wọ́ iná láti Ṣíhónì Ó jó Árì àti Móábù run, àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Ánónì Ègbé ní fún ọ, ìwọ Móábù! Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kémósì! Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀san àti ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ bí ìgbékùn fún Ṣíhónì ọba àwọn Ámórì Ṣùgbọ́n ati bì wọ́n ṣubú A ti pa wọ́n run títí dé Díbónì A sì ti run wọ́n títí dé Nófà, tí ó sì fí dé Médébà Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń gbé ní ilẹ̀ Ámórì Lẹ́yìn ìgbà tí Mósè rán wọn lọ sí Jésírélì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì gba àwọn agbégbé tó yí wọn ká wọ́n sì lé àwọn Ámórì tó wà níbẹ̀ jáde Nígbà náà wọ́n pẹ̀yìn dà wọ́n sì gòkè lọ sí Básánì, Ógì ọba ti Básánì àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó wọ́de ogun jáde lati pàdé wọn ní ojú ogun ní Édírélì Olúwa sọ fún Mósè pé, Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi í lé ọ lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀ Ṣe fún un gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Ṣíhónì ọba Ámórì ẹni tí ó ń jọba ní Hésíbónì Wọ́n sì pa á, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọn kò fi ẹnìkankan sílẹ̀ Wọ́n sì gba ìní ilẹ̀ rẹ̀ Bálákì Ránṣẹ́ Sí Bálámù Nígbà náà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rin ìrìnàjò lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù wọ́n sì pa ibùdó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì tí ó kọjá lọ sí Jẹ́ríkò Nísinsìnyìí Bálákì ọmọ Sípórì rí gbogbo ohun tí àwọn Ísírẹ́lì ti ṣe sí àwọn ará Ámórì, ẹ̀rù sì ba Móábù nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn wà níbẹ̀ nítòótọ́, Móábù kún fún ẹ̀rù nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Móábù sọ fún àwọn àgbààgbà Mídíánì pé, Nísinsìnyìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko Bẹ́ẹ̀ ni Bálákì ọmọ Ṣípórì, tí ó jẹ́ ọba Móábù nígbà náà, rán oníṣẹ́ pé Bálámù ọmọ Béórì, tí ó wà ní Pétórì, ní ẹ̀bá odò ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ Bálákì sọ pé Àwọn ènìyàn kan jáde wá láti Éjíbítì wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ ayé wọ́n sì pa ibùdó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi Nísinsìnyìí wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú Olórí àwọn Móábù àti Mídíánì sì lọ pẹ̀lú owó àyẹ̀wò lọ́nà wọn, Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Bálámù, wọ́n sọ nǹkan tí Bálákì sọ fún wọn Ẹ sùn níbí lálẹ́ yìí Bálámù sọ fún un pé, Èmi ó padà wá fún un yín ní èsì nǹkan tí Olúwa bá wí fún mi Nítorí tí àwọn ìjòyè Móábù dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ Ọlọ́run tọ Bálámù wá ó sì wí pé, Ta ni àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ yìí Bálámù sọ fún Ọlọ́run pé, Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù, rán iṣẹ́ yìí sí mi pé Ènìyàn tí ó jáde láti Éjíbítì wá bo ojú ayé Nísinsin yìí wá kí o wá fi wọ́n bú fún mi Bóyá màá le bá wọn jà èmi ó sì lé wọn jáde   Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún Bálámù pé, Má ṣe bá wọn lọ Ìwọ kò gbọdọ̀ gé ègún lé àwọn ènìyàn náà lórí, nítorí a ti bùkún wọn Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Bálámù dìde ó sì sọ fún àwọn ìjòyè Bálákì pé, Ẹ padà sí orílẹ̀ èdè yín, nítorí tí Olúwa ti kọ̀ láti jẹ́ kí n tẹ̀lé yín Nígbà náà àwọn ìjòyè Móábù sì padà tọ Bálákì lọ wọ́n sì wí pé, Bálámù kọ̀ láti tẹ̀lé wa Nígbà náà Bálákì rán àwọn ìjòyè mìíràn tí wọ́n pọ̀ àwọn tí wọ́n sì níyì ju alákọ́kọ́ lọ Wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Bálámù wọ́n sì sọ pé Èyí ni ohun tí Bálákì ọmọ Sípórì sọ Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun kí ó dè ọ́ lọ́nà láti wá sí ọ̀dọ̀ mi, Nítorí pé èmi yóò fún ọ ní ẹ̀bùn dáradára màá sì ṣe ohunkóhun tí o bá sọ Wá kí o sì wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú fún mi Ṣùgbọ́n Bálámù dá wọn lóhùn pé, Kó dà tí Bálákì bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, n kò ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí kéré tí o kọjá òfin Olúwa Ọlọ́run mi Nísinsìnyìí ẹ dúró níbí di ọjọ́ kejì gẹ́gẹ́ bí àwọn tókù ti ṣe nígbà náà èmi yóò mọ ohun tí Olúwa yóò tún sọ fún mi Ní alẹ́ ọjọ́ náà Ọlọ́run sì tọ Bálámù wá ó sì sọ wí pé, Nígbà tí ọkùnrin yìí ti wá pè ọ́, lọ pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ẹnu nǹkan tí mo sọ fún ọ ni kí o ṣe Bálámù dìde ní òwúrọ̀, ó sì di ẹrù lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ òun pẹ̀lú àwọn ìjòyè Móábù Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bínú gidigidi, áńgẹ́lì Olúwa sì dúró lójú ọ̀nà láti dojú ìjà kọ ọ́ Bálámù ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀ Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì rí áńgẹ́lì Olúwa tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà tí a fà yọ ní ọwọ́ rẹ̀, ó kọjú kúrò ní ọ̀nà lọ sínú oko Bálámù sì lù ú pé kí ó gbé òhun padà lọ sí ojú ọ̀nà Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa dúró ní ojú ọ̀nà tóóró láàrin ọgbà àjàrà, pẹ̀lú ògiri ní ọ̀nà méjèèjì Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì Olúwa , ó lẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ ògiri, ó sì rún ẹsẹ̀ Bálámù mọ́ ògiri Nígbà náà, ó tún nàá, lẹ́ẹ̀kan sí i Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa súnmọ́ wájú ó sì dúró níbi ọ̀nà tóóró níbi tí kò ti sí ọ̀nà láti yípadà, bóyá ní ọ̀tún tàbí òsì Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì Olúwa , ó sì jókó ní abẹ́ Bálámù, inú sì bí i tó sì ná-àn pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀ Nígbà náà Olúwa sí ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì sọ fún Bálámù pé, Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi nà mí lẹ́ẹ̀mẹ́ta Bálámù sọ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pé, Nítorí ìwọ fi mí ṣẹ̀sín! Bí mo bá ní idà ní ọwọ́ ni èmi ì bá pa ọ́ nísinsin yìí Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sọ fún Bálámù pé, Ṣé mi kì í ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni, tí o máa ń gùn ní gbogbo ìgbà, láti ìgbà pípẹ́ wá Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí Rárá, Ó dáhùn Nígbà náà Olúwa sí ojú Bálámù, ó sì rí ángẹ́lì Olúwa tí ó dúró ní oju ọ̀nà pẹ̀lú idà rẹ̀ tí ó fàyọ Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Kí ni ó dé tí o fi na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹ́ta yìí Mo wá síbí láti kọ ojú ìjà sí ọ nítorí ọ̀nà rẹ kò tọ́ níwájú mi Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí mi ó sì yà kúrò fún mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta yìí Tí ó bá jẹ́ wí pé kò yà kúrò Èmi kì ìbá ti pa ọ́ pátapáta nísinsìnyìí, ṣùgbọ́n Èmi yóò sì dá òun sí Bálámù sọ fún ángẹ́lì Olúwa pé, Mo ti dẹ́ṣẹ̀, èmi kò mọ̀ pé o dúró níwájú ọ̀nà láti dojú kọ mí, Nísinsin yìí tí inú rẹ kò bá dùn, èmi ó padà Ańgẹ́lì Olúwa sọ fún Bálámù pé, Lọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin náà, ṣùgbọ́n nǹkan tí mo sọ fún ọ nìkan ni kí o sọ Nígbà náà Bálámù lọ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Bálákì Nígbà tí Bálákì gbọ́ pé Bálámù ń bọ̀ wá, ó jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀ ní ìlú Móábù tí ó wà ní agbégbé Ánónì, ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ̀ Bálákì sì sọ fún Bálámù pé, Ǹjẹ́ èmi kò a ránṣẹ́ kánjúkánjú sí ọ Kí ló dé tí ìwọ kò fi wá sí ọ̀dọ̀ mi Ṣé èmi kò tó láti sọ ọ́ di ẹni ńlá Kíyèsi, èmi ti wá sọ́dọ̀ rẹ nísinsin yìí, Bálámù fẹ̀sì pé Ṣùgbọ́n ṣe mo lè sọ ohunkóhun Mo gbọdọ̀ sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu Nígbà náà Bálámù lọ pẹ̀lú Bálákì sí Kriati-Hosotíà Bálákì rú ẹbọ akọ màlúù pẹ̀lú àgùntàn, ó sì fún Bálámù ní díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Bálákì gbé Bálámù lọ sí òkè Báálì, láti ibẹ̀ ló ti rí apákan àwọn ènìyàn Ọ̀rọ̀ Ìjìnlẹ̀ Àkọ́kọ́ Bálámù Bálámù sọ́ wí pé, Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí, kí o sì mú akọ màlúù méje àti àgbò méje wá fún mi Bálákì ṣe bí Bálámù ti sọ, àwọn méjèèjì fi akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan Nígbà náà Bálámù sọ fún Bálákì pé, Dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan Bóyá Olúwa yóò farahàn mí Ohunkóhun tí ó bá fihàn, mí màá sọ fún ọ Nígbà náà ó sì lọ sí ibi gíga Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀, Bálámù sì sọ pé, Mo tí ṣe pẹpẹ méje, lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan mo ti fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu Bálámù ó wí pé, Padà sí ọ̀dọ̀ Bálákì kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí fún un Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Móábù Nígbà náà ni Bálámù sọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ jáde wí pé Bálákì mú mi láti Árámù wá, ọba Móábù láti òkè ìlà oòrùn wá Ó wí pé, Wá fi Jákọ́bù bú fún mi wá, kí o sì jẹ́rì i sí Ísírẹ́lì Báwo ní èmi ó ṣe fi bú àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wí àwọn tí Olúwa kò bá wí Láti ṣónṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn, láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀ wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀ èdè Ta ni ó lè ka eruku Jákọ́bù tàbí ka ìdámẹ́rin Ísírẹ́lì Jẹ́ kí èmi kú ikú olóòtọ́, kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dàbí ti wọn! Bálákì sọ fún Bálámù pé, Kí lo ṣe fún mi Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀ta mi bú, Ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan Ṣùgbọ́n o bùkún wọn! Ó sì dáhùn wí pé, Sé kí n má sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu Nígbà náà Bálákì sọ fún un pé, Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn wà á rí díẹ̀ Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi Ó sì lọ sí pápá Ṣóímù ní orí òkè Písígà, ó sì kọ́ pẹpẹ méje síbẹ̀ ó sì fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan Bálámù ṣo fún Bálákì pé, Dúró níbí ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ nígbà tí mo bá lọ pàdé rẹ̀ níbẹ Olúwa pàdé Bálámù ó sì fí ọ̀rọ̀ sí ní ẹnu wí pé, Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Bálákì kí o sì jísẹ́ fún un Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì báà tí ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Móábù Bálákì sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, Kí ni Olúwa wí Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ Dìde, Bálákì kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sípórà Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu-un ṣẹ Èmi gba àṣẹ láti bùkún Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jákọ́bù, kò sì rí búburú kankan nínú Ísírẹ́lì Olúwa Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn Ọlọ́run mú wọn jáde láti Éjíbítì wá, wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jákọ́bù, tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Ísírẹ́lì Nísinsìnyìí a ó sọ nípa ti Jákọ́bù àti Ísírẹ́lì, Wo ohun tí Olúwa ti ṣe! Àwọn ènìyàn dìde bí abo kìnnìún wọ́n dìde bí i kìnnìún tí kì í sinmi títí yóò fi pa ìkógún jẹ tàbí mu ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó fi ara pa Nígbà náà ni Bálákì sọ fún Bálámù pé, O ko fi wọ́n bú tàbí bùkún wọn rárá! Bálámù dáhùn pé, Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé mo gbọdọ̀ Ṣe ohun tí Olúwa bá sọ Nígbà náà Bálákì sọ fún Bálámù pé, Wá jẹ́ kí èmi kí ó mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá yóò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí ó fi wọ́n bú láti ibẹ̀ lọ Bálákì gbé Bálámù wá sí orí òkè Péórì, tí ó kọjú sí ihà Bálámù sọ pé, Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí kí o sì pèsè akọ màlúù àti àgbò fún mi Bálákì sì ṣe bí Bálámù ti sọ fún un, ó sì gbé akọ màlúù kan àti àgbò lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan Ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ̀kẹrin Bálámù Nísinsìnyìí nígbà tí Bálámù rí i wí pé ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti bùkún àwọn Ísírẹ́lì, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá ihà Nígbà tí Bálámù wo ìta ó sì rí Ísírẹ́lì tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀ Ó wí pé Bálámù ọmọ Béórì, òwe ẹni tí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀, Òwe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì là Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jákọ́bù, àti ibùgbé rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì! Gẹ́gẹ́ bí àfonífojì tí ó tàn jáde, gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá, gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn, gẹ́gẹ́ bí igi òpépé tí ó wà lẹ́bá odò Omi yóò sàn láti inú garawa èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi Ọba wọn yóò ga ju Ágágì lọ ìjọba wọn yóò di gbígbéga Ọlọ́run mú wọn jáde láti Éjíbítì wá wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Wọ́n jẹ orílẹ̀ èdè run, wọ́n fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́ wọ́n fi idà wọn gún wọn Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún, bí abo kìnnìún ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ, kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú! Nígbà náà ni ìbínú Bálákì sì dé sí Bálámù Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀ta mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí Nísinsìnyìí kúrò lọ́dọ̀ mi kíákíá kí o sì máa relé! Mo sọ wí pé màá sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa kò jẹ́ kí o gba èrè yìí Bálámù dá Bálákì lóhùn, Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé, Kó dà bí Bálákì bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, n kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe Òwe Bálámù ọmọ Béórì, òwe ẹnì tí ojú rẹ̀ ríran kedere, òwe ẹni kan tí etí rẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ẹni gíga jùlọ, tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì sí Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí, Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́ Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jákọ́bù yóò yọ jáde láti Ísírẹ́lì Yóò tẹ̀ fọ́ orí Móábù, yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Ṣéétì Wọn yóò borí Édómù yóò ṣẹ́gun Ṣéérì ọ̀ta rẹ̀, ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì yóò dàgbà nínú agbára Olórí yóò jáde láti Jákọ́bù yóò sì pa àwọn tó ṣẹ́kù nínú ìlú náà run Nígbà náà ni Bálámù rí Ámálékì ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe Ámálékì ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀ èdè, ṣùgbọ́n yóò dahoro níkẹyìn Nígbà náà ní ó rí ará Kénitì ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe Ibùgbé rẹ ní ààbò, ìtẹ́ rẹ ni a tò sínú àpáta ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ará Kenítì ni yóò di píparun nígbà tí Áṣúrì bá mú yín ní ìgbékùn Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀ Áì, ta ni ó lè yè nigbà tí Ọlọ́run bá ṣe èyí Ọkọ̀ yóò wá láti ibùdó kọ̀ Kítímù wọn yóò ṣẹ́gun Áṣù àti Ébérì, ṣùgbọ́n àwọn náà yóò di píparun Nígbà náà ni Bálámù dìde ó sì padà sí ilé rẹ̀, Bálákì sì lọ ní ọ̀nà tirẹ̀ Móábù Tan Ísírẹ́lì Jẹ Nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì dúró ní Ṣítímù, àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Móábù, tí ó pè wọ́n sí bi ẹbọ òrìṣà wọn Àwọn ènìyàn náà jẹun wọ́n sì foríbalẹ̀ níwájú òrìṣà wọn Báyìí ni Ísírẹ́lì ṣe darapọ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì jọ ń sin Báálì ti Péórì Ìbínú Olúwa sì ru sí wọn Olúwa sọ fún Mósè pé Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú Olúwa , kí ìbínú Olúwa lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì Mósè sọ fún àwọn onídàájọ́ Ísírẹ́lì, Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ pa arákùnrin rẹ̀ èyí tí ó darapọ̀ ní fífi orí balẹ̀ fún Báálì ti Peori Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sì mú obìnrin Mídíánì wá ṣíwájú ojú Mósè àti gbogbo ìpéjọ ti Ísírẹ́lì wọ́n sì ń sunkún ní àbáwọlé Àgọ́ Ìpàdé Nígbà tí Fínéhásì, ọmọ Élíásárì, ọmọ Árónì, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìpéjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ Ó sì tẹ̀lé arákùnrin Ísírẹ́lì yìí lọ sínú àgọ́ Ó sì fi ọ̀kọ̀ gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ láti ara ọkùnrin Ísírẹ́lì àti sí ara obìnrin náà Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-àrùn lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dúró ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó kú nínú àjàkálẹ̀-àrùn náà jẹ́ ẹgbàá méjìlá Olúwa sì tún sọ fún Mósè pé, Fínéhásì ọmọ Élíásárì ọmọ Árónì, àlùfáà, ti yí ìbinú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrin wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn Nítorí náà sọ fún un pé èmi ṣe májẹ̀mú àlàáfíà mi pẹ̀lú rẹ̀ Òun àti irú ọmọ rẹ̀ yóò ní májẹ̀mú láéláé fún iṣẹ́ àlùfáà, nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọ́run rẹ̀ láti fi yẹ́ Ọlọ́run sí, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Orúkọ ọmọ Ísírẹ́lì tí a pa pẹ̀lú obìnrin Mídíánì náà ni Símírì, ọmọ Ṣálù, olórí ilé kan nínú àwọn ọmọ Símónì Orúkọ ọmọbìnrin Mídíánì náà tí a pa ni Kósíbì ọmọbìnrin Súrù, tí ṣe olóyè àwọn ẹ̀yà kan nínú ìdílé kan ní Mídíanì Olúwa sì tún sọ fún Mósè pé, Ka àwọn ará Mídíánì sí ọ̀ta, kí o sì pa wọ́n, nítorí pé wọ́n ṣe sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀ta nígbà tí wọ́n tàn yín nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Péórì, àti arábìnrin wọn Kósíbì ọmọbìnrin ìjòyè Mídíánì kan, obìnrin tí a pa nígbà tí àjàkálẹ̀-àrùn ṣẹlẹ̀ nítorí Péórì Ìkànìyàn Ẹlẹ́ẹ̀kejì Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-àrùn Olúwa sọ fún Mósè àti Élíásárì ọmọ Árónì, àlùfáà pé Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n láti ẹni ogun ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Ísírẹ́lì Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Móábù pẹ̀lú Jọ́dánì tí ó kọjá Jẹ́ríkò, Mósè àti Élíásárì àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé, Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ ogun ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mósè Èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jáde láti Éjíbítì wá Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àkọ́bí ọmọkùnrin Ísírẹ́lì, láti ẹni ti ìdílé Hánókù, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hánókù ti jáde wá Láti ìdílé Pálù, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pálù ti jáde wá ti Hésírónì, ìdílé àwọn ọmọ Hésírónì ti Kárímì, ìdílé àwọn ọmọ Kárímì Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé ẹgbẹ̀sán ó dín àádọ́rin Àwọn ọmọkùnrin Pálù ni Élíábù, àwọn ọmọkùnrin Élíábù ni Némúélì àti Dátanì àti Ábírámù Èyí ni Dátanì àti Ábírámù náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Árónì tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kórà nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kórà, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tàlérúgba ọkùnrin Tí wọ́n sì di àmì ìkìlọ̀ Àwọn ọmọ Kórà, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú Àwọn ọmọ ìrán Símónì bí ìdílé wọn ti Némúélì, ìdílé Némúélì ti Jámínì, ìdílé Jámínì ti Jákínì, ìdílé Jákínì ti Ṣérà, ìdílé Ṣérà tí Ṣọ́ọ̀lù, ìdílé Ṣọ́ọ̀lù Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Símónì, ẹgbàámọ́kànlá ó lé igba ọkùnrin Àwọn ọmọ Gádì bí ìdílé wọn ti Ṣéfónì, ìdílé Ṣéfónì ti Hágígì, ìdílé Hágígì ti Ṣúnì, ìdílé Ṣúnì ti Ósínì, ìdílé Ósíní ti Érì, ìdílé Érì ti Árédì, ìdílé Árédì ti Árólì, ìdílé Árólì Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gádì tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Àwọn ọmọ Júdà ni Érì àti Ónánì, ṣùgbọ́n Érì àti Ónánì kú ní ilẹ̀ Kénánì Àti àwọn ọmọ Júdà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn ti Ṣélà, ìdílé Ṣélà ti Pérésì, ìdílé Pérésì ti Sérà, ìdílé Ṣérà Àwọn ọmọ Pérésì ti Hésírónì, ìdílé Hésírónì ti Hámúlù, ìdílé Hámúlù Wọ̀nyí ni ìdílé Júdà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógójì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Àwọn ọmọ Isákárì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn ti Tólà, ìdílé Tólà ti Púfà, ìdílé Púfà ti Jáṣúbù, ìdílé Jáṣúbù ti Ṣímírónì, ìdílé Ṣímírónì Wọ̀nyí ni ìdílé Isákárì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàáméjìlélọ́gbọ̀n ó léọ̀ọ́dúnrún Àwọn ọmọ Ṣebúlúnì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn ti Sẹ́rẹ́dì, ìdílé Ṣẹ́rẹ́dì ti Élónì, ìdílé Élónì ti Jálélì, ìdílé Jálélì Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebúlúnì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Àwọn ọmọ Jósẹ́fù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn Mánásè àti Éfúráímù Àwọn ọmọ Mánásè ti Mákírì, ìdílé Mákírì ti Gílíádì, ìdílé àwọn ọmọ Gílíádì Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gílíádì ti Íésérì, ìdílé Íésérì ti Hélékì, ìdílé Hélékì àti ti Ásíríẹ́lì, ìdílé Ásíríẹ́lì àti ti Ṣékémù, ìdílé Ṣékémù àti Ṣemídà, ìdílé àwọ ọmọ Ṣemídà àti ti Heférì, ìdílé àwọn ọmọ Héférì Wọ̀nyí ni ìdílé Mánásè tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàámẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Éfúráímù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ Ṣútẹ́là, ìdílé àwọn ọmọ Ṣútẹ́là ti Békérì, ìdílé àwọn ọmọ Békérì ti Táhánì, ìdílé àwọn ọmọ Táhánì Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣútélà ti Éránì, ìdílé àwọn ọmo Éránì Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Éfurémù, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàámẹ́rìndínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nì yí tí Bẹ́là, ìdílé àwọn ọmọ Bẹ́là ti Ásíbérì, ìdílé àwọn ọmọ Ásíbérì ti Áhírámù, ìdílé àwọn ọmọ Áhírámù ti Ṣúfámù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣúfámù ti Húfámù, ìdílé àwọn ọmọ Húfámù Àwọn ọmọ Bẹ́là ní pasẹ̀ Árídì àti Náámánì nì yí ti Árádì, ìdílé àwọn ọmọ Árádì ti Náámánì, ìdílé àwọn ọmọ Náámánì Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàáméjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dánì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn ti Ṣúhámù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù Wọ̀nyí ni ìdílé Dánì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàáméjìlélọ́gbọ̀n ó lé irínwó Ti àwọn ọmọ Ásérì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn ti Ímínà, ìdílé àwọn ọmọ Ímínà ti Íṣífì, ìdílé àwọn ọmọ Íṣífì ti Béríà, ìdílé àwọn ọmọ Béríà Ti àwọn ọmọ Béríà ti Hébérì, ìdílé àwọn ọmọ Hébérì ti Mákíẹ́lì, ìdílé àwọn ọmọ Mákíẹ́lì Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Áṣérì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbéje Ti àwọn ọmọ Náfítalì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn ti Jásélì, ìdílé àwọn ọmọ Jásélì ti Gúnì, ìdílé àwọn ọmọ Gúnì ti Jésérì, ìdílé àwọn ọmọ Jéṣérì ti Ṣílémù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣilemù Wọ̀nyí ni ìdílé ti Náfítalì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé egbéje Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ó lé ẹgbẹ̀sán ó dín àádọ́rin Olúwa sọ fún Mósè pé, Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni ín Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrin ńlá àti kékeré Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Léfì tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn ti Gáṣónì, ìdílé àwọn ọmọ Gáṣónì ti Kóhátì, ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì ti Mérárì, ìdílé àwọn ọmọ Mérárì Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Léfì ìdílé àwọn ọmọ Líbínì, ìdílé àwọn ọmọ Hébírónì, ìdílé àwọn ọmọ Málì, ìdílé àwọn ọmọ Múṣì, ìdílé àwọn ọmọ Kórà Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Léfì láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé lẹ́gbẹ̀rún Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn Àwọn wọ̀nyí ni Mósè àti Élíásárì àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́bá odò Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò Kò sí ẹnìkan nínú àwọn tí Mósè àti Árónì àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ihà Sínáì Nítorí Olúwa ti sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kíkú ni wọn yóò kú sí ihà, kò sì sí ẹnìkankan nínú wọn tí kò kú à fi Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnì, àti Jóṣúà ọmọ Núnì Ọmọbìnrin Ṣélóféhátì Ọmọbìnrin Ṣélóféhátì ọmọ Héférì, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírì ọmọ Mánásè tó jẹ́ ìdílé Mánásè, ọmọ Jósẹ́fù wá Orúkọ àwọn ọmọbìnrin náà ni Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tásà Wọ́n súnmọ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé wọ́n sì dúró níwájú Mósè, àti Élíásérì àlùfáà, àti níwájú àwọn olórí àti ìjọ, wọ́n sì wí pé, Baba wa kú sí ihà Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kórà tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa , Ṣùgbọ́n ó kú nítórí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀ Kín ni ó dé tí orúkọ baba wa yóò parẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ nítórí pé kò ní ọmọkùnrin Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrin àwọn arakùnrin baba wa Nígbà náà Mósè mú ọ̀rọ̀ wọn wá ṣíwájú Olúwa Olúwa sì wí fún un pé, Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Ṣélófénátì ń sọ tọ̀nà Ó gbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀ Tí kò bá ní ọmọbìnrin, fi ohun ìní rẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ Tí kò bá ní arakùnrin, fi ogún ìní rẹ̀ fún arákùnrin baba rẹ̀ Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀ Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mósè   Nígbá náà Olúwa sọ fún Mósè pé, Lọ sì orí òkè Ábárímù yìí, kí o sì lọ wo ilẹ̀ tí mo fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Lẹ́yìn ìgbà tí o bá sì ti rí i, ìwọ náà yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí Árónì arákùnrin rẹ ṣe ṣe, nítórí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní Aginjù Ṣínì, tí gbogbo yín se àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn Mósè sọ fún Olúwa wí pé, Jẹ́ kí Olúwa , Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, kí ó yan ọkùnrin kan sí orí ìjọ ènìyàn yìí Láti má a darí wọn, ẹni tí yóò mú wọn jáde, tí yóò sì mú wọn wọlé, gbogbo ènìyàn Olúwa kí yóò dàbí àgùntàn tí kò ní olùsọ́ Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mósè pé, Mú Jóṣúà ọmọ Núnì, ọkùnrin nínú ẹni tí èmi wà, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e Jẹ́ kí ó dúró níwájú Élíásárì àlùfáà àti ojú gbogbo àwọn ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì kí o sì fi àsẹ fún un ní ojú wọn Fún un ní ara àwọn àṣẹ rẹ kí gbogbo ìlú Ísírẹ́lì kí ó lè gbọ́ràn sí i lẹ́nu Kí ó dúró níwájú Élíásárì àlùfáà, tí yóò gba ìpinnu fún láti béèrè Úrímù níwájú Olúwa Gẹ́gẹ́ bí òfin yìí ni òun pẹ̀lú gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì yóò jáde lọ, pẹ̀lú òfin rẹ̀ sì ni wọn ó wọlé Mósè sì se gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un Ó mú Jóṣúà ó sì mú kí ó dúró níwájú Élíásárì àlùfáà àti níwájú gbogbo ìjọ Nígbà náà ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, ó sì fi àṣẹ fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Ọrẹ Ojoojúmọ́ Olúwa sọ fún Mósè pé, Fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin yìí kí o sì wí fún wọn pé Ẹ rí i wí pé ẹ gbé e wá sí iwájú mi ní àkókò tí a ti yàn, oúnjẹ ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná ṣe sí mi, gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí mi Sọ fún wọn, Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ọrẹ sísun ní ojojúmọ́ Pèsè ọ̀dọ́ àgùntàn kan ní òwúrọ̀ àti òmíràn ní àfẹ̀mọ́júmọ́ Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ tí ó jẹ́ ìdámẹ́wàá éfà ìyẹ̀fun dáradára tí a pò pọ̀ mọ́ ìdámẹ́rin hínì òróró tí a yọ lára Ólífì Èyí ni ẹbọ sísun gbogbo ìgbà tí a fi lẹ́lẹ̀ ní òkè Sínáì gẹ́gẹ́ bí olóòrùn dídùn ẹbọ tí a fi iná sun fún Olúwa pẹ̀lú iná Àfikún ọrẹ ohun mímu rẹ gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́rin ti hínì dídé omi mímu tí ó kan pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́ àgùntàn Da ẹbọ mímu náà síta sí Olúwa ní ibi mímọ́ Pèsè ọ̀dọ́ àgùntàn kejì ní àfẹ̀mọ̀júmọ́, pẹ̀lú oríṣìí ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu èyí tí ó pèsè ní òwúrọ̀, èyí ni ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòrùn dídùn sí Olúwa  Ní ọjọ́ ìsinmi, pèsè akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì olọ́dún kan tí kò lábùkù, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ohun jíjẹ tí i ṣe ìdá méjì nínú ìdámẹ́wàá òṣùwọn ìyèfun ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò Èyí ni ẹbọ sísun fún gbogbo ọjọ́ ìsinmi kọ̀ọ̀kan, ní àfikún pẹ̀lú ẹbọ sísun àti ẹbọ ohun mímu  Àti ní ọjọ́ tí o bẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan, kí ẹ̀yin kí ó gbé ẹbọ sísun fún Olúwa pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ ẹbọ ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ pẹ̀lú òróró pẹ̀lú àgbò, ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ tí í ṣe ìdáméjì nínú mẹ́wá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ mọ́ òróró pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́ àgùntàn, ni kí ẹ rú ẹbọ ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a pò pọ̀ mọ́ òróró Èyí ni ẹbọ sísun, òórùn dídùn, àti ẹbọ tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú iná Kí ẹbọ ohun mímu wọn jẹ́ ààbọ̀ òṣùwọ̀n hínì ti ọtí wáìnì, fún akọ màlúù kan, àti ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n hínì fún àgbò kan àti ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n hínì fún ọ̀dọ́ àgùntàn kan Èyí ni ẹbọ sísun tí wọn ó máa rú ní oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu, ẹ gbọdọ̀ fi akọ ewúrẹ̀ kọ̀ọ̀kan fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀  Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ní-ní ni ìrékọjá Olúwa gbọdọ̀ wáyé Ní ọjọ́ kẹẹ́dógún oṣù yìí ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ àjọ̀dún fún ọjọ́ méje kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà Ní ọjọ́ kìn-ní-ní ni kí ẹ ṣe ìpàdé àjọ mímọ́ kí ẹ wá kí ẹ sì má ṣe iṣẹ́ kankan Ẹ rú ẹbọ àfinásun sí Olúwa , ẹ rú u pẹ̀lú ọ̀dọ́ màlúù méjì akọ, ẹbọ sísun pẹ̀lú iná àgbò kan àti ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kí wọn kí ó jẹ́ aláìlábùkù Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá pẹ̀lú ọ̀dọ̀ àgùntàn kọ̀ọ̀kan ida kan nínú mẹ́wà Pẹ̀lú òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún un yín Ṣe eléyí ní àfikún sí ẹbọ sísun àràárọ̀ Báyìí ní kí ẹ ṣe se oúnjẹ fún ẹbọ tí a fi iná ṣe ní ojojúmọ́ fún ọjọ́ méje gẹ́gẹ́ bí olóòrùn dídùn sí Olúwa ó gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí a fi iná ṣe ní àfikún ẹbọ ohun jíjẹ àti ohun mímu Ní ọjọ́ kéje kí ẹ̀yin kí ó ní ìpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe isẹ́ kankan  Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún Olúwa lẹ́yìn àsìkò Àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ se iṣẹ́ kankan Kí ẹ mú ẹbọ sísun ẹgbọrọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kan gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn fún Olúwa Pẹ́lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù ní kí ẹ rú ẹbọ ohun mímu ìdámẹ́ta pẹ̀lú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò pẹ̀lú àgbò kan Àti pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́ àgùntàn méje, kí ó jẹ́ ìdá kan nínú mẹ́wàá Ẹ fi òbukọ kan ṣe ètùtù fún ara yín Ẹ ṣe eléyí papọ̀ ní àfikún ẹbọ ohun mímu yín àti ẹbọ ohun jíjẹ yín Kí ẹ sì ri dájú pé àwọn ẹranko náà jẹ́ aláìlábùkù Àṣè Ìpè  Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù keje, kí ẹ ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan Ọjọ́ ìfúnpè ni ó jẹ́ fún yín Gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa , ẹ pèsè ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù, kí ẹ fi ẹbọ sísun Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kan, àti ìdáméjì nínú mẹ́wàá, òṣùwọ̀n fún àgbò kan, àti ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀dọ́ àgùntàn kan, àti fún ọ̀dọ́ àgùntàn méje Àti òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún yín Pẹ̀lú ẹbọ sísun oṣù àti ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ẹbọ mímu wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn Fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa  Ní ọjọ́ kẹwàá nínú oṣù keje, kí ẹ ṣe àpèjọ mímọ́ Kí ẹ̀yin kí ó ṣẹ́ ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan Kí ẹ̀yin kí ó rú ẹbọ olóòrùn dídùn sí Olúwa , ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kan, kí wọn kí ó sì jẹ́ aláìlábùkù fún yín Pẹ̀lú akọ màlúù, pèsè ìdámẹ́wàá mẹ́ta, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò àti ìdámẹ́wàá méjì òṣùwọ̀n fún àgbò kan, àti fún ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan, ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù àti ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ mímu wọn  Ní ijọ́ kẹẹdógún oṣù kéje, kí ẹ̀yin kí ó ní àpèjọ mímọ́, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan Kí ẹ̀yin kí ó ṣi ṣe àjọyọ̀ fún Olúwa fún ọjọ́ méje Kí ẹ sì rú ẹbọ sísun kan, ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa , ẹbọ tí ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù mẹ́tàlá, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá tí ó jẹ́ ọdún kan, tí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù mẹ́tàlá, pèsè ìyẹ̀fun òṣùwọ̀n ìdámẹ́wàá mẹ́ta tí a fi òróró pò pẹ̀lú ọ̀kọ̀kan, fún àgbò kan, bẹ́ẹ̀ ni fún àgbò méjèèjì, àti fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́ àgùntàn kan Bẹ́ẹ̀ ni fún ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rẹ̀ẹ̀rìnlá Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ọrẹ sísun gbogbo ìgbà ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu rẹ̀  Àti ní ijọ́ kejì ni kí ẹ̀yin kí ó fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù méjìlá, àgbò méjì àti ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá ọlọ́dún kan aláìlábùkù rúbọ Pẹ̀lú fún akọ màlúù, fún àgbò, àti fún ọ̀dọ́ àgùntàn kí ẹ pe ẹbọ ohun jíjẹ, àti ẹbọ ohun mímu, kí ó jẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ mímu  Ní ọjọ́ kẹta, pèsè akọ màlúù mọ́kànlá, àgbò méjì, akọ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọdún kan tí kò ní àbùkù Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti akọ àgùntàn, pèsè ọrẹ ohun jíjẹ àti ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹbọ sísun ìgbàgbogbo pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu  Ní ọjọ́ kẹrin, pèsè akọ màlúù mẹ́wàá, àgbò méjì, àti ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù Àti akọ màlúù, àgbò àti àgùntàn, pèsè ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu  Àti ní ọjọ́ kárùn un, pèsè akọ màlúù mẹ́sàn-án, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn sí ìlànà Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbàgbogbo pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu  Ní ọjọ́ kẹfà, pèsè akọ màlúù mẹ́jọ, àgbò ọlọ́dún kan tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu  Àti ní ọjọ́ keje, pèsè akọ màlúù méje, àgbò méjì, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kan, tí gbogbo rẹ̀ kò sì ní àbùkù Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèṣè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye wọn Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu  Àti ní ọjọ́ kẹjọ kí ẹ̀yin kó ní àpèjọ, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan Kí ẹ̀yin ṣe ìgbékalẹ̀ ẹbọ tí a fi iná ṣe tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa , ẹbọ sísun ti akọ màlúù kan, àgbò ọlọ́dún kan àti ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan méje, gbogbo rẹ̀ tí kò ní àbùkù Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèsè fún wọn ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu  Pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ yín, àti ẹbọ àtinúwá yín, kí ẹ̀yin kí o pèsè fún Olúwa ní àjọ yín, ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ìkẹ́gbẹ́ yín   Mósè sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbogbo ohun tí Olúwa ti paláṣẹ fún un Àwọn Ẹ̀yà Léfì Ìwọ̀nyí ni ìdílé Árónì àti Mósè ní ìgbà tí Olúwa bá Mósè sọ̀rọ̀ ní òkè Sínáì Orúkọ àwọn ọmọ Árónì nìwọ̀nyí, Nádábù ni àkọ́bí, Ábíhù, Élíásárì àti Ítamárì Orúkọ àwọn ọmọ Árónì nìwọ̀n yìí, àwọn àlùfáà tí a fi òróró yàn, àwọn tí a fi joyè àlùfáà láti siṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù ti kú níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n rú iná àjèjì níwájú Olúwa nínú ijù Sínáì, àwọn méjèèjì kò sì ní ọmọ Báyìí Élíásárì àti Ítamárì ló sisẹ́ àlùfáà nígbà ayé Árónì baba wọn Olúwa sọ fún Mósè pé, Kó ẹ̀yà Léfì wá, kí o sì fà wọ́n fún Árónì àlùfáà láti máa ràn-án lọ́wọ́ Wọn yóò máa ṣiṣẹ́ fún un àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn ní Àgọ́ Ìpàdé bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́ Wọn yóò máa tọ́jú gbogbo ohun èlò inú Àgọ́ Ìpàdé, wọn yóò sì máa ṣe ojúṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ṣíṣe iṣẹ́ nínú àgọ́ Fi ẹ̀yà Léfì jìn Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn nìkan ni a fi fún Árónì nínú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Kí o sì yan Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ àlùfáà ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ pípa ni kí ẹ pa á Olúwa tún sọ fún Mósè pé, Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Léfì láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì Ti èmi ni àwọn ọmọ Léfì, nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Éjíbítì ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Ísírẹ́lì yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi Èmi ni Olúwa Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè ní ihà Ṣínáì pé, Ka àwọn ọmọ Léfì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn kí o ka gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè Mósè sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti pa á láṣẹ fún un Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Léfì Gáṣónì, Kóhátì àti Mérárì Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Gáṣónì Líbínì àti Ṣíméhì Àwọn ìdílé Kóhátì ni Ámírámù, Ísíhárì, Hébírónì àti Yúsíélì Àwọn ìdílé Mérárì ni Málì àti Músì Wọ̀nyí ni ìdílé Léfì gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn Ti Gáṣónì ni ìdílé Líbínì àti Ṣíméhì àwọn ni ìdílé Gásónì Iye àwọn ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, jẹ́ ẹgbàata ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ Àwọn ìdílé Gáṣónì yóò pa ibùdó sí ìhà ìwọ̀ oòrùn lẹ́yìn àgọ́ Olórí àwọn ìdílé Gáṣónì ni Eliásáfì ọmọ Láélì Iṣẹ́ àwọn ìdílé Gásónì nínú Àgọ́ Ìpàdé ni pé àwọn yóò máa tọ́jú àgọ́, ìbòrí àgọ́, aṣọ títa ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, aṣọ títa ti àgbàlá, aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, àwọn okùn rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn Ti Kóhátì ní ìdílé Ámírámù, Ísíhárì, Hébírónì àti Yúsíélì, wọ̀nyí ni ìran Kóhátì Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá mẹ́rin ó lé ẹgbẹ̀ta, tí yóò máa ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ Àwọn ìdílé Kóhátì yóò pa ibùdó wọn sí ìhà gúúṣù ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́ Olórí àwọn ìdílé Kóhátì ni Élísáfì ọmọ Yúsíélì Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tabílì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn Élíásárì ọmọ Árónì àlùfáà ni alákóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Léfì Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́ Ti Mérárì ni ìran Málì àti Múṣì, àwọn ni ìran Mérárì Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, èyí tí wọ́n kà jẹ́ igba mọ́kànlélọ́gbọ̀n Olórí àwọn ìdílé ìran Mérárì ni Súríélì ọmọ Ábíháílì, wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́ Àwọn ìran Mérárì ni a yàn fún títọ́jú àwọn férémù àgọ́, ọ̀pá ìdábú rẹ̀, òpó rẹ̀, ihò òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn Iṣẹ́ wọn tún ni títọ́jú àwọn òpó tó yí àgbàlá ká, ihò òpó rẹ̀, èèkàn àti okùn wọn Mósè àti Árónì pẹ̀lú àwọn ọmọ yóò pa àgọ́ ní ìdojúkọ ìwọ̀ oòrùn níwájú Àgọ́ Ìpàdé Iṣẹ́ wọn ni láti máa mójútó iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́ àti láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí a yàn, pípa ni kí ẹ pa á Àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Léfì tí a kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè àti Árónì gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá Olúwa sọ fún Mósè pé, Ka gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin Ísírẹ́lì láti ọmọ oṣù kan ó lé kí o sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn Kí o sì gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Léfì fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Èmi ni Olúwa Mósè sì ka gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un Àpapọ̀ iye àwọn àkọ́bí ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan ó lé, ní àkọsílẹ̀ orúkọ wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé ọ̀rìnlúgba ó dín méje Olúwa tún sọ fún Mósè pé, Gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Léfì dípò ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Tèmi ni àwọn ọmọ Léfì Èmi ni Olúwa Nísinsin yìí, láti lè ra ọ̀rìnlúgba dín méje àkọ́bí àwọn Ísírẹ́lì tó ju iye àwọn ọmọ Léfì lọ, ìwọ yóò gba sẹ́kẹ́lì márùn ún lórí ẹni kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, èyí tí í ṣe ogún gérà Owó tí a fi ra àwọn àkọ́bí ọmọ Ísírẹ́lì tó lé yìí, ni kí o kó fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ Nígbà náà ni Mósè gba owó ìràpádà àwọn ènìyàn tó sẹ́kù lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Léfì ti ra àwọn yóòkù padà Mósè sì gba egbéje ṣékélì ó dín márùndínlógójì gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ lọ́wọ́ àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Mósè sì kó owó ìràpadà yìí fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, bí Olúwa ti paá láṣẹ fún un Jíjẹ́ Ẹ̀jẹ́ Mósè sì sọ fún olórí àwọn ẹ̀yá ọmọ Ísírẹ́lì pé Èyí ni ohun tí Olúwa pa láṣẹ Nígbà tí ọkùnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ ní ìdè kí òun má bà ba ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ó se gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sọ Nígbà tí ọmọbìnrin kan bá sì wà ní ilé baba rẹ̀ tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ tí baba rẹ̀ bá sì gbọ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ìdè rẹ̀ tí kò sì sọ nǹkan kan sí i, kí gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ kí ó dúró àti gbogbo ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ yóò sì dúró Ṣùgbọ́n tí baba rẹ̀ bá kọ̀ fun un ní ọjọ́ tí ó gbọ́, kò sí ọ̀kan nínú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí nínú ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tí yóò dúró Olúwa yóò sì tú u sílẹ̀ nítorí baba rẹ̀ kọ̀ fún-un Tí ó bá sì ní ọkọ lẹ́yìn ìgbà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí lẹ́yìn ìgbà tí ó sọọ̀rọ̀ kan láti ẹnu rẹ̀ jáde nínú èyí tí ó fi de ara rẹ̀ ní ìdè, Tí ọkọ rẹ̀ sì gbọ́ nípa èyí ṣùgbọ́n tí kò sọ nǹkan kan, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tó dúró Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ nígbà tí ó gbọ́, ǹjẹ́ òun yóò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àti ohun tí ó ti ti ẹnu rẹ̀ jáde, èyí tí ó fi de ara rẹ̀ dasán, Olúwa yóò sì dáríjìn ín Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ́ kí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè kí ìdè tí opó tàbí obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ bá ṣe yóò wà lórí rẹ̀ Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tabí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra, tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá sọ wọ́n dasán, nígbà tí ó gbọ́, nígbà náà kò sí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde tí yóò dúró, ọkọ rẹ̀ ti sọ wọ́n dasán, Olúwa yóò tu sílẹ̀ Ọkọ rẹ̀ lè ṣe ìwádìí tàbí sọ ọ́ dasán ẹ̀jẹ́ tàbí ìbúrà ìdè tí ó ti ṣe láti fi de ara rẹ̀ Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ kò bá sọ nǹkan kan sí í nípa rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́, nígbà náà ni ó se ìwádí nípa ẹ̀jẹ́ àti ìbúra ìdè tí ó dè é Kí ọkùnrin náà se ìwádìí lórí rẹ̀ láì sọ nípa rẹ̀ si nígbà tí ó gbọ́ nípa rẹ̀ Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọkùnrin náà bá sọ ọ́ dasán, ní àkókò kan lẹ́yín tí ó ti gbọ́ wọn, nígbà náà ó jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà Èyí ni ìlànà tí Olúwa fún Mósè nípa ìbátan láàrin ọkùnrin àti obìnrin àti láàrin baba àti ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀ tí ó sì ń gbé ní ilé rẹ̀ Gbígbẹ̀san Lára Àwọn Ọmọ Mídíánì Olúwa sọ fún Mósè pé, Gbẹ̀san lára àwọn Mídíánì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Lẹ́yìn ìgbà náà a ó kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ Mósè sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, Ẹ wọ ìhámọ́ra ogun fún àwọn kan nínú yín láti lọ da ojú ìjà kọ àwọn ọmọ Mídíánì láti gba ẹ̀san Olúwa lára wọn Rán ẹgberún ọmọ ogun láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní Ísírẹ́lì Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yan nínú àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún ènìyan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ẹgbàá mẹ́fà ènìyàn tí ó wọ ìhámọ́ra ogun Mósè rán wọn lọ sí ogun, ẹgbẹ̀rún láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú Fínéhásì ọmọ Élíásárì, ti ó jẹ́ àlùfáà, ti òun ti ohun èlò ibi mímọ́ àti ìpè wọ̀n-ọn-nì ní ọwọ́ rẹ̀ Wọ́n dojú ìjà kọ Mídíánì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti láṣẹ fún Mósè, kí wọn sì pa gbogbo wọn Wọ́n sì pa àwọn ọba Mídíánì pẹ̀lú àwọn ìyókù tí wọ́n pa lára wọn ni Éfì, Rékémù, Ṣúrù àti Húrì, àti Rébà ọba Mídíánì márùn ún, wọ́n sì fi idà pa Bálámù ọmọ Béórì Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì mú gbogbo obìnrin Mídíánì ní ìgbékùn àti àwọn ọmọ kékeré wọn, wọ́n sì kó gbogbo ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo agbo ẹran wọn àti gbogbo ẹrù wọn Wọ́n finá jó gbogbo ìlú wọn àti ibùdó wọn Wọ́n sì kó gbogbo ìní wọn, àti ènìyàn àti ẹran Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí wọ́n bàjẹ́ àti ènìyàn àti ẹran wá sọ́dọ̀ Mósè àti Élíásárì àlùfáà, àti sọ́dọ̀ ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ibùdó àgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò Mósè, Élíásárì àlùfáà àti gbogbo olórí ìgbéríko lọ láti lọ bá wọn ní ìta ibùdó Inú bí Mósè sí àwọn olórí ọmọ ogun, pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹ̀rún àti olórí ọrọrún tí wọ́n ti ogun dé Mósè sì bèèrè wí pé, Ẹ̀yin ha dá gbogbo àwọn obìnrin sí bí Àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Bálámù, àwọn ní ó ṣe okùnfà yíyí àwọn ọ̀mọ̀ Ísírẹ́lì padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa nínú èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Péórì, nibi tí àjàkálẹ̀-àrùn ti kọlu àwọn ènìyàn Olúwa Nísinsìnyìí, pa gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó ti súnmọ́ ọkùnrin, Ṣùgbọ́n kí o dá obìnrin tí kò bá tí ì sún mọ́ ọkùnrin sí fún ara yín Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti pa ènìyàn tàbí fọwọ́ kan ẹni tí a pa gbọdọ̀ dúró ní ìta ibùdó àgọ́ fún ọjọ́ méje, Ní ọjọ́ kẹ́ta àti ọjọ́ kéje ẹ gbọdọ̀ ya ara yín àti ẹni tí ẹ kó lẹ́rú sí mímọ́ Kí ẹ̀yin kí ó ya aṣọ yín sí mímọ́ àti gbogbo ohun tí a fi awọ ṣe àti gbogbo iṣẹ́ irun ewúrẹ́ àti ohun tí a fi igi ṣe Élíásárì àlùfáà sì wí fún àwọn olórí ogun náà pé, Èyí ní ìlànà òfin tí Olúwa fi lélẹ̀ ní àṣẹ fún Mósè Kìkì i wúrà, fàdákà, idẹ, irin, tanńganran àti òjé Ohunkóhun tí ó lè la iná ni kí ẹ̀yin ó mú la iná, nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́ Ṣùgbọ́n ẹ ó ò fi omi ìyàsímímọ́ sọ ọ́ di mímọ́ Àti gbogbo ohun tí kò lè la iná kọjá ni kí a mú la inú omi Ní ọjọ́ kéje, ẹ fọ aṣọ yín, ẹ̀yin yóò sì mọ́, nígbà náà ní ẹ̀yin yóò lè wọ inú ibùdó àjọ Olúwa sọ fún Mósè pé, Ìwọ àti Élíásárì àlùfáà àti àwọn olórí ilé baba ìjọ ni kí o ka iye àwọn ènìyàn àti ẹranko tí a kó ní ìgbékùn Pín ohun ìní àti ìkógún náà láàrin àwọn ọmọ ogun náà tí ó kópa nínú ogun náà àti láàrin gbogbo ìjọ Kí o sì gba ìdá ti Olúwa lọ́wọ́ àwọn ológun tí wọn jáde lọ sí ogun náà ọ̀kan nínú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ènìnyàn àti nínú màlúù àti nínú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti nínú agbo ẹran Gbà ìdá yìí lára ààbọ̀ ìpín ti wọn, kí o sì fún Élíásárì àlùfáà, fún ẹbọ ìgbésókè Olúwa Lára ààbọ̀ ti Ísírẹ́lì, yan ọ̀kan kúrò nínú àádọ́ta, yálà ènìyàn, ẹran ọ̀sìn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹ̀yà ẹranko mìíràn Kó wọn fún àwọn Léfì, tí ó dúró fún olùtọ́jú àgọ́ Olúwa Nígbà náà Mósè àti Élíásárì àlùfáà ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mósè Èrè tí ó kù lára ìkógun tí àwọn ọmọ ogun kó jẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àgùntàn Ẹgbàá mẹ́rìndínlógójì màlúù ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, Pẹ̀lú obìnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógún, ni kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí Ìpín ààbọ̀ àwọn tí ó jáde lọ sí ogun sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínláàdọ́san ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ àgùntàn Tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n àgùntàn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógún, tí ìdá Olúwa sì jẹ́ méjìléláàdọ́rin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún, ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta, tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ mọ́kànlélọ́gọ́ta Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ ìdá ti Olúwa sì jẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n Mósè fi ìdá náà fún Élíásárì, àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìdá ti Olúwa , gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè Ààbọ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí Mósè yà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọkùnrin tí ó ja ogun àgùntàn, pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún màlúù tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ ) Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Mósè yan ọ̀kan lára àádọ́ta ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ Olúwa Pẹ̀lú àwọn olórí tí ó wà lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rin ogun náà, àti àwọn balógun ọrọọrún wá sọ́dọ̀ Mósè Wọ́n sì sọ fún un pé, Ìránṣẹ́ rẹ ti ka àwọn ọmọ ogun náà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú wa, kò sì sí ìkọkan tó dín Nítorí náà làwa ṣe mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa , gbogbo ọrẹ wíwà tí a ní, wúrà, ẹ̀wọ̀n, àti júfù, àti òrùka àmi, àti òrùka etí, àti ìlẹ̀kẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ọkàn an wa níwájú Olúwa Mósè àti Élíásárì àlùfáà, gba wúrà náà lọ́wọ́ ọ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ Gbogbo wúrà tí àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún mú wá fún Mósè àti Élíásárì, èyí tí ó jẹ́ ẹbọ ìgbésókè fún Olúwa jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé àádọ́ta ṣékélì Nítorí ológun kọ̀ọ̀kan ti kó ẹrù fún ara rẹ̀ Mósè àti Élíásárì àlùfáà gba wúrà náà lọ́wọ́ àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti lọ́wọ́ balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wọ́n sì ko wá sínú Àgọ́ Ìpàdé fún ìrántí àwọn Ísírẹ́lì níwájú Olúwa Àwọn Ẹ̀yà Ìkọjá-Odò Jọ́dánì Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn àti ohun ọ̀sìn rí wí pé ilé Jásérì àti Gádì dára fún ohun ọ̀sìn Nígbà náà wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Mósè àti Élíásárì àlùfáà àti sí olórí gbogbo ìlú, wọ́n sì wí pé, Átarótì, Díbónì, Jásérì, Nímírà, Hésíbónì, Élíálì, Sébámù, Nébò, àti Béónì Ni ilẹ̀ tí Olúwa ti ṣẹ́gun níwájú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì tí ó sì dára fún ohun ọ̀sìn, ṣáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ohun ọ̀sìn Tí a bá rí ojú rere rẹ, wọ́n wí, jẹ́ kí a fi ilẹ̀ yìí fún ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní Má se jẹ́kí a rékọjá odò Jọ́dánì Mósè sọ fún àwọn ọmọ Gádì àti fún ọmọ Rúbẹ́nì pé, Ṣé kí àwọn arákùnrin yín lọ sí ogun, kí ẹ̀yin kí ó sì jókó sí bí Kí ni ó dé tí o fi mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti lọ sí ibi ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn Èyí ni nǹkan tí baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadesi-Báníyà láti lọ wo ilẹ̀ náà Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ sí Àfonífojì Ésíkólù tí wọ́n rí ilẹ̀ náà, wọ́n mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn Ìbínú Olúwa sì dìde sí wọn ní ọjọ́ náà, ó sì búra, wí pé Nítorí wọn kò tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó gòkè láti Éjíbítì ni yóò rí ilẹ̀ tí mo pinnu gẹ́gẹ́ bí ìbúra fún Ábúráhámù, fún Ísáákì àti fún Jákọ́bù kò sí ẹnìkankan àyàfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ti Kénísì àti Jóṣúà ọmọ Núnì, nítorí wọ́n tẹ̀lé Olúwa tọkàntọkàn Ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì mú wọn rìn ní ihà fún ogójì ọdún, títí tí àwọn ìran tí wọ́n ṣe búburú ní ojú rẹ̀ fi lọ Níbí ni ẹ̀yin wà, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ̀yin dìde ní ipò bàbá yín, ẹ sì jẹ́ kí ìbínú gbígbóná Olúwa ru sí Ísírẹ́lì Tí ẹ̀yin bá yípadà ní ẹ̀yìn rẹ̀ yóò sì fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí sílẹ̀ ní ihà, ìwọ yóò sì mú-un ṣe ìparun Nígbà náà wọ́n wá sí òkè ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, Àwa yóò fẹ́ láti kọ́ ilé ẹran níhínyìí fún ohun ọ̀sìn wa, àti ìlú fún àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa Ṣùgbọ́n àwa ṣetán láti dira ogun ṣááju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí tí a yóò fi mú wọn dé ọ̀dọ̀ wọn lákokò yìí, àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa yóò gbé inú ìlú tí a mọ odi sí fún ìdábòbò wọn lọ́wọ́ olùgbé ilẹ̀ náà A kì yóò padà sí ilẹ̀ wa láì ṣe pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti gba ogún wọn A kì yóò gba ogún kankan pẹ̀lú wọn ní òdìkejì Jọ́dánì, nítorí ogún ti wa, ti wá sí ọ̀dọ̀ wa ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì Nígbà náà ni Mósè sọ fún wọn pé, Tí ẹ̀yin yóò bá pa ara yín lára, níwájú Olúwa fún ogún Bí gbogbo yín yóò bá lọ sí Jọ́dánì ní ìhámọ́ra níwájú Olúwa , títí yóò fi lé àwọn ọ̀ta rẹ̀ kúrò níwájú rẹ̀ Tí a ó sì fi ṣe ilẹ̀ náà níwájú Olúwa ẹ̀yin lè padà tí yóò sì di òmìnira lọ́wọ́ ìdè níwájú Olúwa àti Ísírẹ́lì Ilẹ̀ yìí yóò sì jẹ́ ti yín níwájú Olúwa Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kọ̀ láti ṣe èyí, ẹ̀yin yóò máa dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa kí ẹ̀yin kí ó sì mọ̀ dájú pé ẹ̀ṣẹ̀ yín yóò fi yín hàn Ẹ kọ́ ilé fún àwọn obìnrin yín àti ọmọ wẹ́wẹ́ yín, àti ilé fún agbo ẹran yín, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó ṣe ohun tí ẹ ti pinnu Àwọn ọmọ Gádì àti ọmọ Rúbẹ́nì sọ fún Mósè pé, Àwa ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa wa ti paláṣẹ Àwọn ọmọ wa àti ìyàwó wa, àwọn agbo ẹran àti ohun ọ̀sìn wa yóò dúró ní ìlú Gílíádì Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gbogbo ọkùnrin tí ó wọ ìhámọ́ra ogun, yóò ré kọjá lọ láti jà níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí olúwa wa ti sọ Nígbà náà ni Mósè pàṣẹ nípa wọn fún Élíásárì àlùfáà àti Jóṣúà ọmọ Núnì àti sí gbogbo olórí ìdílé ẹ̀yà Ísírẹ́lì Ó wí fún wọn pé, Tí àwọn ọmọ Gádì àti ọmọ Rúbẹ́nì, gbogbo ọkùnrin tí ó wọ ìhámọ́ra fún ogun rékọjá odò Jọ́dánì pẹ̀lú níwájú Olúwa , nígbà tí ẹ ṣegun ilẹ̀ náà níwájú yín, Fún wọn ní ilẹ̀ Gílíádì gẹ́gẹ́ bí ìní wọn Ṣùgbọ́n tí wọn kò bá fẹ́ bá yín rékọjá pẹ̀lú ìhámọ́ra, wọn gbọdọ̀ gba ìní wọn pẹ̀lú yín ní Kénánì Àwọn ọmọ Gádì àti ọmọ Rúbẹ́nì dáhùn pé, Iránṣẹ́ rẹ yóò ṣe ohun tí Olúwa ti sọ A máa rékọjá níwájú Olúwa lọ sí Kénánì pẹ̀lú ìhámọ́ra, ṣùgbọ́n ẹrù tí a jogún yóò wà ní ẹ̀bá Jọ́dánì Nígbà náà Mósè fún àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ọmọ Jóṣẹ́fù ìjọba Ṣíhónì ọba àwọn ọmọ Ámórì àti ìjọba Ógù ọba Básánì ní gbogbo ilẹ̀ náà pẹ̀lú ìlú rẹ̀ àti agbégbé tí ó yí i ka Àwọn ará Gádì wọ́n kọ́ Dídónì, Átarótù, Áróérì Pẹ̀lú Átírótù Ṣófánì, Jásérì, àti Jógbénà Pẹ̀lú Bétínímírà, àti Bétí-Áránì ìlú olódi, àti agbo fún àgùntàn Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì sì kọ́ Hésíbónì, Élíálì, Kíríátaímù, pẹ̀lú Nébò pẹ̀lú Báálì-Méónì, àti Síbímà Wọ́n sì sọ ìlú tí wọ́n tún kọ́ ní orúkọ mìíràn Àwọn ọmọ Mákírì ọmọ Mánásè lọ sí Gílíádì, wọ́n sì lé àwọn ọmọ Ámórì tí ó wà níbẹ̀ Mósè sì fi àwọn ọmọ Gílíádì fún àwọn ọmọ Mákírì àwọn ìrán Mánásè, wọ́n sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀ Jáírì, ọmọ Mánásè gba ibùjókòó wọn, ó sì pè wọ́n ní Háfótù Jáírì Nébà gbà Kénátì àti àwọn ìtẹ̀dó rẹ̀, ó sì pè é ní Nóbà lẹ́yìn orúkọ ara rẹ̀ Ìpele Ìrìnàjò Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Wọ̀nyí ni ìrìnàjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ẹsẹẹsẹ, nígbà tí wọ́n tí ilẹ̀ Íjibítì jáde wá pẹ̀lú àwọn ogun wọn, nípa ọwọ́ Mósè àti Árónì Mósè sì kọ̀wé ìjáde lọ wọn ní ẹsẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ìrìnàjò wọn, nípa àṣẹ Olúwa Wọ̀nyí sì ni ìrìnàjò wọn gẹ́gẹ́ bí ìjáde lọ wọn Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò láti Rámésesì ní ọjọ́ kẹ́ẹdógún osù kìn-ín-ní, ọjọ́ kan lẹ́yìn àjọ Ìrékọja Wọ́n yan jáde pẹ̀lú ìgboyà níwájú gbogbo àwọn ará Éjíbítì Tí wọ́n sì ń sin gbogbo àkọ́bí wọn, ẹni tí Olúwa ti gbé lulẹ̀ láàrin wọn nítorí tí Olúwa ti mú ẹ̀san wá sórí àwọn òrìṣà wọn Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Rámésesì wọ́n sì pàgọ́ sí Ṣúkótù Wọ́n kúrò ní Súkótù, wọ́n sì pàgọ́ sí Étamù, ní ẹ̀bá ihà Wọ́n kúrò ní Étamù, wọ́n padà sí Háhírótù sí ìlà oòrùn Báálì ti Ṣéfónì, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Mégídólù Wọ́n sì dìde láti lọ kúrò ní ìwájú Háhírótù, wọ́n sì la àárin òkun kọjá lọ sí ihà Wọ́n sì rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní ihà Étamù, wọ́n sì pàgọ́ sí Márà Wọ́n kúrò ní Márà wọ́n sì lọ sí Élímù, níbi tí orísun omi méjìlá àti igi ọ̀pẹ àádọ́rin gbé wà, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀ Wọ́n kúrò ní Élímù wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun Pupa Wọ́n kúrò ní ẹ̀bá Òkun Pupa wọ́n sì pàgọ́ sínú ihà Ṣínì Wọ́n kúrò nínú ihà Ṣínì wọ́n sì pàgọ́ sí ihà Dófákà Wọ́n kúrò ní Dófákà wọ́n sì pàgọ́ ní Álúṣì Wọ́n kúrò ní Álúṣì wọ́n sì pàgọ́ ní Réfídímù níbi tí kò sí omi fún àwọn ènìyàn náà láti mu Wọ́n kúrò ní Refídímù wọ́n sì pàgọ́ ní ihà Ṣínáì Wọ́n kúrò ní ihà Ṣínáì wọ́n sì pàgọ́ ní Kabirotu-Hátafà Wọ́n kúrò ní Kabirotu-Hátafà wọ́n sì pàgọ́ ní Hásérótì Wọ́n kúrò ní Hásérótì wọ́n sì pàgọ́ ní Rítímà Wọ́n kúrò ní Rítímà wọ́n sì pàgọ́ ní Rímónì-Pérésì Wọ́n kúrò ní Rímóni Pérésì wọ́n sì pàgọ́ ní Líbínà Wọ́n kúrò ní Líbínà wọ́n sì pàgọ́ ní Rísà Wọ́n kúrò ní Rísà wọ́n sì pàgọ́ ní Kehelátà Wọ́n kúrò ní Kehelátà wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Ṣéférì Wọ́n kúrò lórí òkè Ṣéférì wọ́n sì págọ́ ní Hárádà Wọ́n kúrò ní Hárádà wọ́n sì pàgọ́ ní Mákélótì Wọ́n kúrò ní Mákélótì wọ́n sì pàgọ́ ní Táhátì Wọ́n kúrò ní Táhátì wọ́n sì pàgọ́ ní Térà Wọ́n kúrò ní Térà wọ́n sì pàgọ́ ní Mítíkà Wọ́n kúrò ní Mítíkà wọ́n pàgọ́ ní Hásímónà Wọ́n kúrò ní Hásímónà wọ́n sì pàgọ́ ní Mósérótù Wọ́n kúrò ní Mósérótù wọ́n sì pàgọ́ ní Bene-Jákánì Wọ́n kúrò ní Bene-Jákánì wọ́n sì pàgọ́ ní Hori-Hágidigádì Wọ́n kúrò ní Hori-Hágidigádì wọ́n sí pàgọ́ ní Jótíbátà Wọ́n kúrò ní Jótíbátà wọ́n sì pàgọ́ ní Ábírónà Wọ́n kúrò ní Ábírónà wọ́n sì pàgọ́ ní Esoni-Gébérì Wọ́n kúrò ní Esoni-Gébérì wọ́n sì pàgọ́ ní Kádésì nínú ihà Ṣínì Wọ́n kúrò ní Kádésì wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Hórì, lẹ́bá Édómù Nípa àsẹ Olúwa , Árónì àlùfáà gùn orí òkè Hórì, níbẹ̀ ni ó kú Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kárun, ọdún ogójì, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ilẹ̀ Éjíbítì jáde wá Árónì jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún ó lé mẹ́ta ní ìgbà tí ó kú sí orí òkè Hórì Àwọn ará Kénánì, ọba Árádì, tí ń gbé ìhà gúṣù ní ilẹ̀ Kénánì gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bọ̀ Wọ́n kúrò ní orí òkè Hórì, wọ́n sì pàgọ́ ní Ṣálímónà Wọ́n kúrò ní Ṣálímónà wọ́n sì pàgọ́ ní Púnónì Wọ́n kúrò ní Púnónì wọ́n sì pàgọ́ ní Óbótù Wọ́n kúrò ní Óbótù wọ́n sì pàgọ́ ní Iye-Ábárímù, ní agbégbé Móábù Wọ́n kúrò ní Íyímù wọ́n sì pàgọ́ ní Díbónì-Gádì Wọ́n kúrò ní Dibónì-Gádì wọ́n sì pàgọ́ ní Alimoni-Díbílátamù Wọ́n kúrò ní Alimoni-Díbílátaímù wọ́n sì pàgọ́ sí orí òkè Ábárímù lẹ́bá Nébò Wọ́n kúrò ní orí òkè Ábárímù wọ́n sì pàgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́bá Jọ́dánì ní ìkọjá Jẹ́ríkò Níbí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù wọ́n pàgọ́ lẹ́gbẹ́ Jọ́dánì láti Bẹti-Jéíóù títí dé Abeli-Sítímù Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, lẹ́bá Jọ́dánì, létí Jẹ́ríkò, Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí o sì wí fún wọn pé, Ní ìgbà tí ẹ̀yin bá ń rékọjá odò Jọ́dánì lọ sí Kénánì, Lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín Run gbogbo àwòrán ère wọn àti gbogbo ère dídá wọn, kí ẹ sì wó gbogbo ibi gíga wọn palẹ̀ Ẹ gba ilẹ̀ náà, kí ẹ̀yin sì máa gbé inú ún rẹ̀, nítorí èmi ti fi ilẹ̀ náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín Ẹ̀yin pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú kèké, gẹ́gẹ́ bí ìdílé yín Fún ọ̀pọ̀ ni kí ẹ̀yin ó fi ilẹ̀ ìní púpọ̀ fún, àti fún díẹ̀, ni kí ẹ̀yin kí ó fi ilẹ̀ ìní díẹ̀ fún Ohunkóhun tí ó bá bọ́ sí ọ̀dọ̀ wọn nípa kèké yóò jẹ́ ti wọn Pín wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìran wọn  Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá lé àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, àwọn tí ẹ bá jẹ́ kí ó kù yóò di ọfà nínú ojú yín, àti ẹ̀gún ní ìhà yín Wọn yóò fún yín ní wàhálà ní ilẹ̀ náà tí ẹ̀yin yóò gbé Nígbà náà, èmi yóò ṣe sí yín, ohun tí mo ti rò láti ṣe sí wọn   Ààlà Ti Kénánì Olúwa sọ fún Mósè pé, Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún wọn pé Tí ẹ bá wọ Kénánì, ilẹ̀ tí a ó fi fún yín, gẹ́gẹ́ bí ogún yín yóò ní ààlà wọn yí  Ìhà gúṣù yín yóò bọ́ sí ara ihà Ṣínì lẹ́bá Édómù, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà-gúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀, Kọjá lọ sí Síkọ́píọ́nì, tẹ̀ṣíwájú lọ si Sínì kó bọ́ si gúsù Kadesi-Báníyà, kí o sì dé Hasari-Ádárò, kí o sì kọjá sí Ásímónì Níbẹ̀ ni yóò ti padà, papọ̀ mọ́ odò Éjíbítì, tí yóò sì parí ní òpin Òkun  Ìhà ìwọ̀ oòrùn yín yóò jẹ́ òpin lórí Òkun ńlá Èyí yóò jẹ́ ààlà yín lórí ìhà-ìwọ̀ oòrùn  Fún ààlà ìhà-àríwá, fa ìlà láti òkun ńlá lọ sí orí òkè Hórì Àti láti orí-òkè Hórì sí Lébò Hámátì Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Sédádì, Tẹ̀ṣíwájú lọ sí Sífírónì, kí o sì fò pín si ní Hasari-Énánì, Èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá  Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ ti yín ní ìhà ìlà oòrùn láti Hasari-Énánì lọ dé Ṣéfámù Ààlà náà yóò ti Séfámù sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ríbílà ní ìhà-ìlà oòrùn Háínì, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kínérétì ní ìhà ìlà oòrùn Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jọ́dánì, yóò sì dópin nínú Òkun  Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà   Mósè pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún Olúwa ti paláṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́san, àti ààbọ̀ Nítorí ará ilẹ ẹ̀yà ti Rúbẹ́nì, ẹ̀yà ti Gádì àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Mánásè ti gba ogún ti wọn Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún ti wọn ní ìhà Jódánì létí i Jéríkò, Gábásì, ní ìhà ìlà oòrùn Olúwa sọ fún Mósè pé, Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin náà tí yóò pín ilẹ̀, náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún Élíásárì àlùfáà àti Jóṣúà ọmọ Núnì Kí o sì yan olórí kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà Èyí ni orúkọ wọn Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnè, láti ẹ̀yà Júdà Ṣémúélì ọmọ Ámíhúdì, láti ẹ̀yà Ṣíméónì Élídádì ọmọ Kísílónì, láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì Búkì ọmọ Jógílì, láti ẹ̀yà olórí àwọn ọmọ Dánì Háníélì ọmọ Éfódù, láti ẹ̀yà Mánásè, olórí àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù, Kémúélì ọmọ Ṣífílánì, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ, Éfúráímù, ọmọ Jóṣẹ́fù Élísáfánì ọmọ Pánákì, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Ṣébúlunì Pátíélì ọmọ Ásánì, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísákárì Áhíhúdù ọmọ Ṣélómì, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Áṣérì Pédàhẹ́lì ọmọ Ámíhúdì, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Náfitalì Èyí ni àwọn ẹni tí Olúwa yàn láti pín ogún náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ Kénánì Ìlú Fún Àwọn Ọmọ Léfì Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù ní Jọ́dánì tí ó rékọjá láti Jẹ́ríkò, Olúwa sọ fún Mósè pé, Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fún àwọn Léfì ní ilẹ̀ láti gbé lára ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jogún Kí ẹ sì fún wọn ní ilẹ̀ lára pápá oko tútù, káàkiri ìlú Nígbà náà, wọn yóò ní ìlú tí wọn yóò gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn, ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú gbogbo ìní wọn Ilẹ̀ pápá oko tútù káàkiri ìlú tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Léfì, wíwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́ ẹsẹ̀ bàtà láti ògiri ìlú náà Lẹ́yin náà, wọn ẹgbẹ̀ẹ́dogun ẹṣẹ̀ bàtà lápá ibi ìhà ìlà oòrùn ẹgbẹ̀ẹ́dógún ẹṣẹ̀ bàtà ní ìhà gúsù, ẹgbẹ̀ẹ́dógún ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, àríwá Pẹ̀lú ìlú ní àárin Wọn yóò ní agbégbé yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà Mẹ́fà lára ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì yóò jẹ́ ìlú ibi ìsásí, tí ẹni tí ó bá pa ènìyàn yóò sá sí Ní àfikún, ẹ fún wọn ní méjìlélógójì ìlú sí i Ní gbogbo rẹ̀, kí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì ní éjìdínláàdọ́ta ìlú lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀ Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún wọn Nígbà tí ẹ bá rékọjá odò Jọ́dánì sí Kénánì, Yan àwọn ìlú kan láti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìlú ìsásí fún yín, kí apani tó pa ènìyàn ní àìmọ̀ máa sá lọ síbẹ̀ Wọn yóò jẹ́ ibi ìsásí kúrò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí ẹní tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn má baà kú kí ó tó dúró níwájú àwọn ìjọ àwọn ènìyàn ní ìdájọ́ Mẹ́fà nínú ìlú tí ẹ ó fi fún wọn yóò jẹ́ ìlú ààbò fún yín Yan ìlú mẹ́ta ní ìhà ti Jọ́dánì, kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ìhà Kénánì tí yóò máa jẹ́ ìlú ìsásí Ìlú mẹ́fà yìí yóò jẹ́ ìlú ìsásí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, fún àlejò àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé láàrin wọn, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ sá lọ ṣíbẹ̀  Bí ọkùnrin kan bá fi ohun èlò irin lu ènìyàn tí ó kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pá, apànìyàn náà Tàbí tí ènìyàn bá mú òkúta tí ó lè pa ènìyàn lọ́wọ́ tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa apànìyàn náà Tàbí tí ènìyàn bá mú ohun èlò igi ní ọwọ́ ọ rẹ̀ tí ó sì lẹ̀ ẹ́ pa ènìyàn, tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni pípa ní a ó pa apànìyàn náà Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà tí ó bá bá a, yóò pa á Tí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń yan odì pẹ̀lú ìríra tí ẹlòmíràn tàbí ju nǹkan sí i pẹ̀lú èrò, tí ó sì kú Tàbí pẹ̀lú ìjà gbangba lù ú pẹ̀lú ìkúùkù tí ó sì kú, pípa ni a ó pa ẹni bẹ́ẹ̀ apànìyàn ni Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà tí ó bá bá a  Ṣùgbọ́n bí ó bá fi nǹkan gún un lójijì láìṣọ̀ta, tàbí tí ó sọ ohunkóhun lù ú láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe tàbí, láìri, ju òkúta sí tí ó lè pa á, tí ó sì kú, nígbà tí kì í ṣe ọ̀ta rẹ̀, láti ṣe é léṣe, Àwọn àpèjọ gbúdọ̀ dájọ́ láàrin rẹ̀ àti olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Àpèjọ gbọ́dọ̀ dá ààbò bo ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn, kí a sì ran-an padà lọ sí ìlú ìsásí tí ó ti wá Ó gbúdọ̀ dúró níbẹ̀ títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú, ẹni tí a fi àmì òróró yàn  Ṣùgbọ́n ti ẹni tí a fi sùn kan bá jáde kọjá ààlà ìlú ìsásí tí ó sá sí Tí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ sì ri ní ìta ìlú náà, olùgbẹ̀san lè pa ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn láì jẹ́bi ẹ̀sùn ìpànìyàn Ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn gbọdọ̀ dúró nínú ìlú ìsásí títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú lẹ́yìn ikú olórí àlùfáà, ni ó tó lè padà sí ibi tí dúkìá rẹ̀ wà  Wọ̀nyí ni ó jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún yín ní ìran yín tó ń bọ̀, ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé  Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn gbọdọ̀ kú gẹ́gẹ́ bí apànìyàn lórí ìjẹ́rìí àwọn ènìyàn Ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí kanṣoṣo Kì yóò jẹ́ri sí ẹnìkan láti pa  Má ṣe gba ohun ìràpadà fún ẹ̀mí olùpànìyàn, tí ó yẹ kí ó kú A gbọ́dọ̀ pa á  Má ṣe gba ìràsílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá lọ sí ìlú ìsásí, pe kí ó padà máa gbé ní ilẹ̀ tirẹ̀ kí ó tó di ìgbà ikú olórí àlùfáà  Má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ wà di àìmọ́ Ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́ Atúnṣe kì yóò sí fún ilẹ̀ tí a ti ta ẹ̀jẹ̀ lé lórí, àyà fi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ta á sílẹ̀ Má se sọ di àìmọ́, ilẹ̀ tí ẹ ń gbé, àti èyí tí mo ń gbé, nítorí Èmi JÈHÓFÀ, ń gbé láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì   Ogún Ọmọbìnrin Ṣélófíhádì Àwọn olórí ìdílé Gílíádì, ọmọkùnrin Mákírì ọmọ Mánásè tí ó wá láti ara ìdílé ìrán Jósẹ́fù wá, wọ́n sì sọ̀rọ̀ níwájú Mósè àti àwọn olórí, àwọn ìdílé Ísírẹ́lì Wọ́n sọ pé, Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún olúwa mi láti fi ilẹ̀ yìí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ogún nípa kèké ṣíṣẹ́ Ó pa á láṣẹ fún ọ láti fi ogún Ṣélófíhádì arákùnrin wa fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ Wàyí, tí wọn bá fẹ́ ọkùnrin láti ẹ̀yà Ísírẹ́lì mìíràn nígbà náà a ó gba ogún un wọn kúrò nínú ogún ìran wa, a ó sì fi kún ogún ẹ̀yà tí a fẹ́ wọn sí Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gbàá kúrò nínú ìpín ilẹ̀ ogún ti wa Nígbà tí ọdún Júbélì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá dé, a ó pa ogún wọn pọ̀ mọ́ ẹ̀yà tí wọ́n fẹ́ wọn sí, a ó sì gba ogún ẹ̀yà wọn kúrò lọ́wọ́ babańlá wọn Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa , Mósè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Ohun ti ẹ̀yà àwọn ìrán Jóṣẹ́fù ń ṣọ tọ̀nà Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Ṣélófíhádì Wọ́n lè fẹ́ ẹni tí ọkàn wọn fẹ́, kìkì pé wọ́n fẹ́ nínú ẹ̀yà ìdílé baba wọn Kò sí ogún kan ní Ísírẹ́lì tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà mìíràn, nítorí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì ni yóò fi ilẹ̀ ogún ẹ̀yà tí wọ́n jogún láti ọ̀dọ̀ babańlá wọn pamọ́ Gbogbo ọmọbìnrin tí ó bá jogún ilẹ̀ nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ fẹ́ ènìyàn nínú ẹ̀yà ìdílé baba rẹ̀, kí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì lè ní ìpín nínú ogún baba wọn Kò sí ogún kankan tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà òmíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà ọmọ Ísírẹ́lì gbọdọ̀ tọ́jú ilẹ̀ tí ó jogún Nígbà náà, àwọn ọmọbìnrin Ṣẹ́lófẹ́hádì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè Nítorí pé a gbé Málà, Tírísà, Hógílà, Mílíkà, àti Nóà, àwọn ọmọbìnrin Ṣélófẹ́hádì ní ìyàwó fún àwọn ọmọ arákùnrin baba wọn Wọ́n fẹ́ ọkọ nínú ìdílé ìrán Mánásè, ọmọ Jóṣẹ́fù ogún wọn kù nínú ìdílé àti ẹ̀yà baba wọn Wọ̀nyí ni àṣẹ àti ìdájọ tí Olúwa ti ipaṣẹ̀ Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́bá Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò Àwọn Ọmọ Kóhátì Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé Ka iye àwọn ọmọ Kóhátì láàrin àwọn ọmọ Léfì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú Àgọ́ Ìpàdé Wọ̀nyí ni iṣẹ́ àwọn ọmọ Kóhátì, láti tọ́jú àwọn ohun èlò mímọ́ jùlọ Nígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀ṣíwájú, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sí aṣọ ìbòrí rẹ̀, wọn yóò sì fi bo àpótí ẹ̀rí Wọn yóò sì fi awọ ewúrẹ́ bò ó, lórí awọ ewúrẹ́ yìí ni wọn ó tẹ̀ bọ ààyè rẹ̀ Lórí tabilì ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, wọn ó sì kó àwọn àwo, páànù, àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu àkàrà tó sì máa ń wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀ Lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò da, wọn ó tún fi awọ ewúrẹ́ bò ó, wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀ Kí wọn kí ó fi aṣọ aláwọ̀ búlù bọ ọ̀pá fìtílà àti fìtílà rẹ̀, àti àwo ìkó ẹ̀mu sí, àti gbogbo ohun èlò òróró rẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ Kí wọn ó fi awọ ẹran yí fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ, kí wọn kí ó sì gbé e lé orí férémù tí wọn yóò fi gbé e Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀ Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù Kí wọn ó kó eérú kúrò lórí pẹpẹ idẹ, kí wọn ó sì tẹ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò lé e lórí Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èèlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwo kòtò Kí wọn ó fi àwọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpo rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀ Lẹ́yìn tí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èèlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀ṣíwájú, kí àwọn ọmọ Kóhátì bọ́ ṣíwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú Àwọn ọmọ Kóhátì ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú Àgọ́ Ìpàdé Iṣẹ́ Élíásárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àmójútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èèlò ibi mímọ́ Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé, Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kóhátì kúrò lára àwọn ọmọ Léfì Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má baà kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálukú àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kóhátì kò gbọdọ̀ wọlé láti wo àwọn ohun mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú kan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kú Olúwa sọ fún Mósè pé Tún ka iye àwọn ọmọ Gáṣónì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Gáṣónì, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àti ní ẹrù rírù Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti Àgọ́, ti Àgọ́ Ìpàdé àti ìborí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé, Aṣọ títa ti àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà, okùn àti àwọn ohun èlò mìíràn tí à ń lò fún gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí Àwọn ọmọ Gáṣónì ni yóò ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ pẹ̀lú àwọn nǹkan wọ̀nyí Gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Gáṣónì yálà ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ní ẹrù rírù ni, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa darí wọn ìwọ ni kí o sì yàn ẹrù tí oníkálùkù yóò rù fún un Èyí ni iṣẹ́ ìdílé àwọn Gáṣónì ni Àgọ́ Ìpàdé Ítamárì, ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni yóò sì jẹ alábojútó iṣẹ́ wọn Ka iye àwọn ọmọ Mérárì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé Iṣẹ́ tí wọn yóò sì máa ṣe nínú Àgọ́ Ìpàdé nìyìí gbígbẹ́ àwọn férémù àgọ́, pákó ìdábú rẹ̀, òpó àti ihò òpó rẹ̀, Pẹ̀lú gbogbo òpó tó yí àgbàlá ká àti ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn kí o sì yan ohun tí oníkálùkù yóò rù fún un Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Mérárì, bí wọn yóò ti máa ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé lábẹ́ àkóso Ítamárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà Mósè àti Árónì pẹ̀lú àwọn olórí ìjọ ènìyàn ka àwọn ọmọ Kóhátì nípa ìdílé àti ilé baba wọn Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé Iye wọn nípa ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá ó dín àádọ́ta Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Kóhátì tó ń ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé tí Mósè àti Árónì kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè Wọ́n ka àwọn ọmọ Gáṣónì nípa ìdílé àti ile baba wọn Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, gbogbo àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó lé ọgbọ̀n Èyí jẹ́ àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Gásónì, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé Mósè àti Árónì se bí àṣẹ Olúwa Wọ́n ka àwọn ọmọ Mérárì nípa ìdílé àti ilé baba wọn Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Mérárì Mósè àti Árónì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè Báyìí ni Mósè, Árónì àti olórí ìjọ ènìyàn ka gbogbo ọmọ Léfì nípa ìdílé àti ilé baba wọn Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn tó sì ń ru àwọn erù inú Àgọ́ Ìpadé Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá lé lẹ́gbàarin ó dín ogún Wọ́n yan iṣẹ́ àti àwọn ohun tí ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa gbé fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Mósè Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Wíwà ní mímọ́ ibùdó Olúwa sọ fún Mósè pé Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má báà ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrin wọn Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀ wọ́n lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mósè Olúwa sọ fún Mósè pé Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìsòótọ́ sí Olúwa , ẹni náà jẹ̀bi Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀ Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn ún rẹ̀ lée, kí ó sì fi fún ẹni tí Òun jẹ̀bi rẹ̀ Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó sún mọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti Olúwa , ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà Gbogbo ọrẹ ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ tirẹ̀ Ọrẹ ohun mímọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ti oun nikan Ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá fún àlùfáà yóò jẹ́ ti àlùfáà   Olúwa sọ fún Mósè wí pé, Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìsòótọ́ sí i, Nípa mímú kí ọkùnrin mìíràn bá a lò pọ̀ tí ó sì fi èyí pamọ́ fún ọkọ rẹ̀, tí a kò si gbá a mú nínú ìwà àìmọ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkọ rẹ̀ débi pé ó ń furà sí ìyàwó rẹ̀ yìí tí ìyàwó rẹ̀ sì wà ní àìmọ́ nítòótọ́, tàbí tí ẹ̀mí owú bá bà lé ọkùnrin kan tó sì ń jowú ìyàwó rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní mímọ́, nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n éfà ìyẹ̀fun bálì Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí  Àlùfáà yóò sì mú-un wá ṣíwájú Olúwa Àlùfáà yóò sì bu erùpẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ sínú omi mímọ́ tó bù láti ìkòkò amọ̀, Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì tú irun orí obìnrin náà lée lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnra rẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́ Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní se ọ́ níbi Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá ti yapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ, tí o bá ti ba ara rẹ jẹ́ nípa jíjẹ́ kí ọkùnrin tí kì í se ọkọ rẹ bá ọ lò pọ̀, nígbà náà ni àlùfáà yóò mú obìnrin náà búra, yóò sọ fún obìnrin náà pé Kí Olúwa sọ ọ́ di ẹni ègún àti ẹni ìbáwí láàrin àwọn ènìyàn rẹ nípa mímú kí itan rẹ jẹrà, kí ikùn rẹ sì wú Ǹjẹ́ kí omi yìí tí ń mú ègún wá wọ inú ara rẹ, kí ó mú ikùn rẹ̀ wú, kí ó sì mú itan rẹ̀ jẹra dànù  Obìnrin náà yóò sì wí pé, Àmín Bẹ́ẹ̀ ni kó rí  Nígbà náà ni àlùfáà yóò kọ ègún yìí sínú ìwé, yóò sì sìn ín sínú omi kíkoro náà Àlùfáà yóò sì mú kí obìnrin náà mu omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí, omi náà yóò wọ inú rẹ̀ yóò sì fa ìrora kíkorò fún obìnrin náà bí ó bá jẹ̀bi Àlùfáà yóò gba ọrẹ ohun jíjẹ náà lọ́wọ́ rẹ̀, yóò fì í ṣíwájú Olúwa , yóò sì mú iná sórí pẹpẹ Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ọrẹ ohun jíjẹ nàà, yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lẹ́yìn tí ó ti mú kí obìnrin náà mu omi Bí ó bá ti mú obìnrin yìí mu omi náà, bí ó bá sì jẹ́ pé obìnrin náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ó sì se àìsòótọ́ sí ọkọ rẹ̀, omi tí ń mú ègún wá, yóò wọ ara rẹ̀, yóò fa ìrora kíkorò fún un, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan rẹ̀ yóò sì jẹrà dànù, yóò sì di ẹni ègún láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé obìnrin náà kò ba ara rẹ̀ jẹ́, tó sì jẹ́ mímọ́, yóò bọ́ nínú ẹ̀bi, yóò sì le bímọ  Èyí ni òfin owú jíjẹ nígbà tí obìnrin tó wà lábẹ́ ọkọ bá ṣe aṣemá ṣe, tí ó bá ba ara rẹ̀ jẹ́ Tàbí nígbà tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkùnrin kan nítorí pé ó fura sí ìyàwó rẹ̀ Àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí fún un Ara ọkọ rẹ̀ mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ṣùgbọ́n obìnrin náà yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀   Òfin Fún Násírì Olúwa sọ fún Mósè pé Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì, ẹ̀jẹ́ ìyara-ẹni-ṣọ́tọ̀ sí Olúwa nípa àìgé irun orí Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ yàgò fún wáìnì tàbí ọtí líle, ọtí wáìnì kíkan àti àwọn ohun mímu mìíràn tó bá kan Kò gbọdọ̀ mu èso àjàrà tàbí kí ó jẹ èṣo àjàrà tútù tàbí gbígbẹ Níwọ̀n ìgbà tí ó sì jẹ́ Násírì, ní kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi èṣo àjàrà ṣe, ìbá à ṣe kóró tàbí èèpo rẹ̀  Ní gbogbo ìgbà ẹ̀jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, kí abẹ kankan má ṣe kàn án ní orí Ó gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ títí tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa yóò fi pé ó gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn Ní gbogbo àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú ènìyàn Ìbá à ṣe òkú baba, àti ìyá rẹ̀, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí àbúrò rẹ̀, kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí wọn, nítorí pé àmì ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run wà ní orí rẹ̀ Ní gbogbo àsìkò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa  Bí ẹnìkan bá kú ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òjijì, tí ó sì ba irun rẹ̀ tó yà sọ́tọ̀ jẹ́ ó gbọdọ̀ gé irun rẹ̀ ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe ọjọ́ keje Ní ọjọ́ kẹjọ, yóò mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé méjì wá sọ́dọ̀ àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé Àlùfáà yóò fi ọ̀kan rúbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun láti fi ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa wíwà níbi tí òkú ènìyàn wà Yóò sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà gan an Ó gbọdọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ sí Olúwa fún àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi Kò sì ní í ka àwọn ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó tí ba ara rẹ̀ jẹ́ ní àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀  Èyí ni òfin fún Násírì nígbà tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé Wọn ó mu wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé Níbẹ̀ ni yóò ti mú ọrẹ wá fún Olúwa , akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun àti ẹgbọ̀rọ̀-àgùntàn ọlọ́dún kan, tí kò ní àbùkù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò kan tí kò ní àbùkù fún ọrẹ àlàáfíà, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu, apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà ṣe, àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun dáradára pò pọ̀ mọ́ òróró àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a fi òróró sọjọ̀ lé lórí  Àlùfáà yóò gbé gbogbo rẹ̀ wá ṣíwájú Olúwa , yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun Àlùfáà yóò fi àgbò náà rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa , pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà yóò rú ẹbọ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu  Nígbà náà ni Násírì náà yóò fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé Yóò fi irun náà sínú iná tó wà lábẹ́ ẹbọ àlàáfíà  Lẹ́yìn tí Násírì bá ti fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ tan, àlùfáà yóò mú apá àgbò bíbọ̀, àkàrà aláìwú kan àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà láti inú apẹ̀rẹ̀ yóò sì kó gbogbo rẹ̀ lé e lọ́wọ́ Àlùfáà yóò fí gbogbo rẹ̀ níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, wọ́n jẹ́ mímọ́, wọ́n sì jẹ́ ti àlùfáà pẹ̀lú ìgẹ̀ tí a fì àti itan tí wọ́n mú wá Lẹ́yìn èyi, Násírì náà lè mu wáìnì  Èyí ni òfin Násírì tó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ rẹ̀ sí Olúwa , yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Násírì, ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn tó lágbára láti mú wá Ó gbọdọ̀ mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin Násírì   Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ẹ sọ fún wọn pé   Kí Olúwa bùkún un yín Kí ó sì pa yín mọ́ Kí Olúwa kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára Kí ó sì ṣàánú fún un yín Kí Olúwa bojú wò yín Kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà   Báyìí ni wọn ó ṣe fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Èmi ó sì bùkún wọn Ọrẹ Níbi Ìyàsímímọ́ Àgọ́ Nígbà tí Móṣè ti pári gbígbé àgọ́ dúró, ó ta òróró sí i, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, Ó tún ta òróró sí pẹpẹ, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀ Nígbà náà ni àwọn olórí Ísírẹ́lì, àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, àwọn alábojútó àwọn tí a kà náà mú ọrẹ wá Wọ́n mú ọrẹ wọn wá ṣíwájú Olúwa kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́fà ti abo, àti akọ màlúù kan láti ọ̀dọ̀ olórí kọ̀ọ̀kan àti kẹ̀kẹ́ ẹrù kan láti ọ̀dọ̀ olórí méjì Wọ́n sì kó wọn wá sí iwájú àgọ́ Olúwa sọ fún Mósè pé Gba gbogbo nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn, kí wọ́n ba à lè wúlò fún iṣẹ́ inú Àgọ́ Ìpàdé Kó wọn fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ṣe nílò rẹ̀ Mósè sì kó àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù àti akọ màlúù náà fún àwọn ọmọ Léfì Ó fún àwọn ọmọ Gáṣónì ní kẹ̀kẹ́ méjì àti akọ màlúù mẹ́rin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́ O fún àwọn ọmọ Mérárì ní kẹ̀kẹ́ mẹ́rin àti akọ màlúù mẹ́jọ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́ Gbogbo wọn wà lábẹ́ àkóso Ítamárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà Ṣùgbọ́n Mósè kò fún àwọn ọmọ Kóhátì ní nǹkan kan nítorí pé èjìká wọn ni wọn yóò fi ru àwọn ohun mímọ́ èyí tí ó jẹ́ ojúṣe tiwọn Nígbà tí a ta òróró sórí pẹpẹ Àwọn olórí mú àwọn ọrẹ wọn wá fún ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá ṣíwájú pẹpẹ Nítorí tí Olúwa ti sọ fún Mósè pé, Olórí kọ̀ọ̀kan ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni yóò máa mú ọrẹ tirẹ̀ wá ṣíwájú pẹpẹ Ẹni tí ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kìn-ín-ni Náṣónì ọmọ Ámínádábù láti inú ẹ̀yà Júdà Ọrẹ rẹ̀ jẹ́ àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò ti fàdákà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun, Akọ ewurẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, Màlúù méjì, àgbò márùn ún, akọ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà Wọ̀nyí ni ọrẹ Násónì ọmọ Ámínádábù Ní ọjọ́ kéjì ni Nétaníẹ́lì ọmọ Súárì olórí àwọn ọmọ Ísákárì mú ọrẹ tirẹ̀ wá Ọrẹ tí ó kó wá ní àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje sékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ sékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí, Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-un àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-un tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà Èyí ni ọrẹ Nètaníẹ́lì ọmọ Súárì Élíábù ọmọ Hélónì, olórí àwọn ọmọ Sébúlónì ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹ́ta Àwọn ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọn rẹ̀ jẹ́ àádóje àti ṣékélì fàdákà, àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn ún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn o fi rú ẹbọ àlàáfíà Èyí ni ọrẹ Élíábù ọmọ Hélónì Élíṣúrì ọmọ Ṣédéúrì olórí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ kẹrin Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí, Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà Èyí ni ọrẹ Élísúrì ọmọ Ṣédéúrì Ṣélúmíélì ọmọ Suriṣádáì, olórí àwọn ọmọ Símónì ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ karùn-ún Ọrẹ tí ó kó wá ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ́ Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà Èyí ni ọrẹ Sélúmíélì ọmọ Surisádáì Eliásáfì ọmọ Déúélì olórí àwọn ọmọ Gáádì ní ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹfà Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò kan tí iwọn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò bí ẹbọ ohun jíjẹ Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà Èyí ni ọrẹ Eliásáfì ọmọ Déúélì Élísámà ọmọ Ámíhúdì, olórí àwọn ọmọ Éfúráímù ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ keje Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà Èyí ni ọrẹ Élísámà ọmọ Ámíhúdì Gàmálíèlì ọmọ Pédáṣúrì, olórí àwọn ọmọ Mánásè ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹjọ Ọrẹ tirẹ̀ ni, àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà Èyí ni ọrẹ Gámálíélì ọmọ Pédásúrì Ábídánì ọmọ Gídíónì, olórí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹsan-an Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà Èyí ni ọrẹ Ábídánì ọmọ Gídíónì Áhíésérì ọmọ Ámíṣádáyì, olórí àwọn ọmọ Dánì ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹwàá Ọrẹ rẹ̀ ni àwo sílifà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Màlúù méjì, àgbò márùn-ùn, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fí rú ẹbọ àlàáfíà Èyí ni ọrẹ ọmọ Dánì Págíélì ọmọ Ókíránì, olórí àwọn ọmọ Áṣérì ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kọkànlá Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun Akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fí rú ẹbọ àlàáfíà Èyí ni ọrẹ Págíélì ọmọ Ókíránì Áhírà ọmọ Énánì, olórí àwọn Náfítanì ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kejìlá Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, àti àwokótó tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì méwàá tí ó kún fún tùràrí Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà Èyí ni ọrẹ Áhírà ọmọ Énánì Wọ̀nyí ni ọrẹ tí àwọn olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n ta òróró sí i lórí àwo fàdákà méjìlá, àwokòtò méjìlá, àwo wúrà méjìlá Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá ṣékélì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwó wúrà méjìlá tí tùràrí kún inú wọn ṣékélì mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ Àpapọ̀ ìwọ̀n gbogbo àwo wúrà jẹ́ ọgọ́fà ṣékélì Àpapọ̀ iye ẹran fún ẹbọ sísun jẹ́ akọ ọ̀dọ́ màlúù méjìlá, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan méjìlá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ Akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ méjìlá Àpapọ̀ iye ẹran fún ọrẹ àlàáfíà jẹ́ màlúù mẹ́rìnlélógún , ọgọ́ta àgbò, ọgọ́ta akọ ewúrẹ́ àti ọgọ́ta akọ ọ̀dọ́ màlúù ọlọ́dún kan Wọ̀nyí ni ọrẹ ìyàsímímọ́ pẹpẹ lẹ́yìn tí a ta òróró sí i Nígbà tí Mósè wọ inú Àgọ́ Ìpàdé láti bá Olúwa sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ̀rọ̀ sí i láti àárin àwọn kérúbù méjì láti orí ìtẹ́ àánú tó bo àpótí ẹ̀rí, ohùn náà sì bá Mósè sọ̀rọ̀ Gbígbé Ọ̀pá Fìtílà Ró Olúwa sọ fún Mósè pé Bá Árónì sọ̀rọ̀ kí o wí fún un pé Nígbà tí ó bá ń to àwọn fìtílà, àwọn fìtílà méjèèje gbọdọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí àyíká níwájú ọ̀pá fìtílà   Árónì sì ṣe bẹ́ẹ̀ ó to àwọn fìtílà náà tí wọ́n sì fi kojú ṣíwájú lórí ọ̀pá fìtílà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Bí a ṣe ṣe ọ̀pá fìtílà náà nìyìí A ṣe é láti ara wúrà lílù láti ìṣàlẹ̀ títí dé ibi ìtànná rẹ̀ Wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà náà gẹ́gẹ́ bí bátànìi tí Olúwa fi han Mósè Olúwa sọ fún Mósè pé Yọ àwọn ọmọ Léfì kúrò láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́ Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́ Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ Jẹ́ kí wọn ó mú akọ ọ̀dọ́ màlúù pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ tí í ṣe ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò, kí ìwọ náà mú akọ ọ̀dọ́ màlúù kejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ Ìwọ ó sì mú àwọn ọmọ Léfì wá ṣíwájú Àgọ́ Ìpàdé, kí o sì kó gbogbo àpapọ̀ ọmọ Ísírẹ́lì jọ ṣíbẹ̀ pẹ̀lú Báyìí ni kí o mú àwọn ọmọ Léfì wá ṣíwájú Olúwa , gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì yóò sì gbọ́wọ́ lé àwọn ọmọ Léfì lórí Árónì yóò sì mú àwọn ọmọ Léfì wá ṣíwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá, kí wọn lè máa ṣiṣẹ́ Olúwa Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Léfì bá gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ ọmọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun sí Olúwa , láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Léfì Mú kí àwọn ọmọ Léfì dúró níwájú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì sí Olúwa Báyìí ni ìwọ yóò ṣe ya ọmọ Léfì sọ́tọ̀, kúrò láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù, àwọn ọmọ Léfì yóò sì jẹ́ tèmi Lẹ́yìn tí ó ti wẹ àwọn ọmọ Léfì mọ́, tí ó sì ti gbé wọn kalẹ̀ bí ẹbọ fífì nígbà náà ni kí wọn ó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú Àgọ́ Ìpàdé Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátapáta nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkunrin gbogbo Ísírẹ́lì Nítorí pé gbogbo àkọ́bí ọmọ lọ́kùnrin ní Ísírẹ́lì jẹ́ tèmi, ti ènìyàn àti ti ẹranko, láti ọjọ́ tí mo ti pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Éjíbítì ni mo ti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ara mi Mo sì ti gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí ọmọ ọkùnrin nínú Isireli Nínú Ísírẹ́lì, mo fi àwọn ọmọ Léfì fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé fun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti láti máa ṣe ètùtù fún wọn kí àjàkálẹ̀-àrùn má ba à kọlu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi mímọ́ Mósè, Árónì àti gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì ṣe fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Àwọn ọmọ Léfì wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn Árónì sì mú wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú Olúwa , Árónì sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́ Lẹ́yìn èyí àwọn ọmọ Léfì lọ sínú àgọ́ ìpàdé láti lọ máa ṣiṣẹ́ wọn lábẹ́ àbojútó Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ Wọ́n ṣe fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Olúwa sọ fún Mósè pé, Èyí ni ohun tó jẹ mọ́ àwọn ọmọ Léfì Láti ọmọ ọdún kẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni kí ó máa kópa nínú iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé Ṣùgbọ́n ẹni tó bá ti pé ọmọ àádọ́ta ọdún gbọdọ̀ síwọ́ nínú iṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn nínú àgọ́, kí wọ́n sì má ṣiṣẹ́ mọ́ Wọ́n le máa ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́ nínú Àgọ́ Ìpàdé ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan Báyìí ni kí o ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn ọmọ Léfì Àṣè Ìrékọjá Olúwa sọ fún Mósè nínú ihà Ṣínáì ní oṣù kìn-ín-ní ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì wí pé Mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní àsìkò rẹ̀ Ẹ ṣe é ní àsìkò rẹ̀ gan-an ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ Mósè sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa pa àjọ ìrékọjá mọ́ Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní ihà Ṣínáì ní ìdajì ọjọ́ kẹ́rìnlá oṣù kìn-ín-ní Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè Àwọn díẹ̀ nínú wọn kò lè ṣe àjọ Ìrékọjá lọ́jọ́ náà nítorí pé wọ́n di aláìmọ́ nítorí òkú ènìyàn Nítorí èyí wọ́n wá sọ́dọ̀ Mósè àti Árónì lọ́jọ́ náà Wọ́n sọ fún Mósè pé, A di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ló dé tí a kò fi ní í le è fi ọrẹ wa fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ará Ísírẹ́lì yòókù ní àsìkò tí a ti yàn Mósè sì dá wọn lóhùn pé, Ẹ dúró kí n ba lè mọ ohun tí Olúwa yóò pa láṣẹ nípa yín Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì Bí ẹnìkan nínú yín tàbí nínú ìran yín bá di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn tàbí bí ó bá lọ sí ìrìnàjò síbẹ̀ yóò pa àjọ Ìrékọjá mọ́ Wọn yóò ṣe ti wọn ní ìdajì ọjọ́ kẹ́rìnlá oṣù kejì Wọn yóò jẹ ẹran náà, pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewúro Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀ Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣẹ àjọ Ìrékọjá Ṣùgbọ́n bí ẹnì kan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ Ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ Olúwa wá ní àsìkò tí ó yẹ Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀  Bí àlejò tí ń gbé láàrin yín bá fẹ́ ṣe Àjọ Ìrékọjá ó gbọdọ̀ pa á mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin rẹ̀ Ìlànà kan náà ni kí ẹ ní fún àlejò àti àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ yín   Ní ọjọ́ tí wọ́n gbé àgọ́, èyí tí í ṣe àgọ́ ẹ̀rí, dúró, ìkúùkù àwọ̀sánmọ̀ bò ó mọ́lẹ̀ Ìkúùkù náà sì dàbí iná lórí àgọ́ láti ìrọ̀lẹ́ títí di òwúrọ̀ Bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe títí, ìkúùkù yóò bò ó lọ́sán, ìrísí rẹ̀ sì dàbí iná lálẹ́ Nígbàkígbà tí ìkúùkù yìí bá ká sókè kúrò lórí àgọ́ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò dìde láti máa lọ ibikíbi tí ìkúùkù náà bá dúró sí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò pa ibùdó wọn sí Nípa àṣẹ Olúwa ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jáde lọ, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń pa ibùdó wọn Nígbà tí ìkúùkù bá dúró sórí àgọ́, àwọn náà yóò dúró sí ibùdó Nígbà tí ìkúùkù bá dúró sórí àgọ́ fún ìgbà pípẹ́, síbẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa wọn kò sì ní gbéra láti lọ Ìgbà mìíràn ìkúùkù lè wà lórí àgọ́ fún ọjọ́ díẹ̀ ṣíbẹ̀ ní àṣẹ Olúwa , wọn yóò dúró ní ibùdó, bí ó sì tún yá, ní àṣẹ rẹ̀ náà ni wọn yóò gbéra Ìgbà mìíràn ìkúùkù lè dúró láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀, nígbà tó bá sì kúrò ní àárọ̀, wọn ó gbéra Ìbá à ṣe ní ọ̀sán tàbí òru, ìgbàkigbà tí ìkúùkù bá tó kúrò náà ni wọn ó tó gbéra Ìbá à ṣe fún ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí ọdún kan ni ìkúùkù fi dúró sórí àgọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò dúró ní ibùdó wọn, wọn ò ní í gbéra ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá lọ sókè ni wọn ó tó o gbéra Nípa àṣẹ Olúwa ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń gbéra Wọ́n gbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè Ìran ti Ọbadáyà Èyí ni Olúwa Ọlọ́run wí nípa Édómù Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá A sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo aláìkọlà láti sọ pé, Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i Kíyèsí i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrin àwọn aláìkọlà ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọpọ̀, Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta, tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga, ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé, Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀ Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì, Bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárin àwọn ìràwọ̀, Láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀, ni Olúwa wí Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá, Bí àwọn ọlọ́sà ní òru, Áà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́ ṣé wọn kò jalè tó bí wọ́n ti fẹ́ Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá, ṣé wọn kò ni fi èésẹ́ èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀ Báwo ni a ṣe se àwárí nǹkan Ísọ̀ tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀ Olúwa wí pé, Ní ọjọ́ náà, Èmi yóò pa àwọn ọlọ́gbọ́n Édómù run, àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Ísọ̀ A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, Ìwọ Témánì, gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Ísọ̀ ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà Nítorí ìwà ipá sí Jákọ́bù arákùnrin rẹ, ìtìjú yóò bò ọ, a ó sì pa ọ run títí láé Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apákan, ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ, tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jérúsálẹ́mù, ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ, ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀ ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Júdà, ní ọjọ́ ìparun wọn ìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ, ní ọjọ́ àjálù wọn Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀ nínu ìdàmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó, ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nà láti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó sẹ́kù wọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé lórí gbogbo àwọn aláìkọlà Bí ìwọ ti se, bẹ́ẹ̀ ni a ó se sí ìwọ náà ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ se mu lórí òkè mímọ́ mi Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo aláìkọlà yóò máa mu títí Wọn yóò mu wọn yóò sì gbémì Wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò wà rí Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Síónì Wọn yóò sì jẹ́ mímọ́ àti ilé Jákọ́bù yóò sì ní ìní wọn Ilé Jákọ́bù yóò sì jẹ́ iná àti ilé Jósẹ́fù ọwọ́ iná ilé Ísọ̀ yóò jẹ àkékù koríko wọn yóò fi iná sí i, wọn yóò jo run Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Ísọ̀ Nítorí Olúwa ti wí i Àwọn ará Gúsù yóò ni òkè Ísọ̀, àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni ilẹ̀ àwọn ará Fílísítíánì ní ìní Wọn yóò sì ni oko Éfúráímù àti Samáríà Bẹ́ńjámínì yóò ní Gílíádì ní ìní Àwọn ìgbèkùn Ísírẹ́lì tí ó wà ní Kénánì yóò ni ilẹ̀ títí dé Séréfátì àwọn ìgbékùn láti Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Séfárádì yóò ni àwọn ìlú Gúsù ní ìní Àwọn olùgbàlà yóò sì gòkè Síónì wá láti jọba lé orí àwọn òkè Ísọ̀ Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa Ìkíni Èmi Pọ́ọ̀lù, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìyìn rere Jésù Kírísítì àti Tímótíù arákùnrin wa Sí Fílímónì ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábàáṣiṣẹ́ wa, sí Áfíà arábìnrin wa, sí Ákípọ́sì ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kírísítẹ́nì tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ Oore-Ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jésù Kírísítì Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi, nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jésù Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́ Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábàápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ̀ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọ-ingbọ-in, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kírísítì wá Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lara Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ninú Kírísítì mo ní ìgboyà púpọ̀ láti pàṣẹ ohun ti ó yẹ kí ó ṣe fún ọ, ṣíbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́ Èmi gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù, arúgbó, àti nísinsìnyìí òǹdè Jésù Kírísítì Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Ónísímu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá Èmi rán an nísinsìn yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó baà dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìyìn rere ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má baà jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa Nítorí náà bí ìwọ bá kà mí sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tẹ́wọ́ gbà á bí ìwọ yóò ti tẹ́wọ́ gbà mí Bí ó bá ti ṣe ọ́ ní ibi kan tàbí jẹ ọ́ ní gbésè ohun kan, kà á sí mi lọ́rùn Èmi Pọ́ọ̀lù, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ níí sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbésè ara rẹ Èmi ń fẹ́, arákùnrin, pé kí èmi kí ó lè ni àǹfààní kan láti ọ̀dọ̀ rẹ nínú Olúwa fi ayọ̀ rẹ kún ọkàn mi nínú Jésù Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́ràn, ni mo fi kọ ìwé yìí ránsẹ́ sí ọ Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò se ju bí mo ti béèrè lọ Ó ku ohun kan Ṣe ìtọ́jú ìyara àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín Ẹ́páfírà, òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi nínú Kírísítì Jésù kí ọ Máàkù kí ọ pẹ̀lú Ańsíbákù, Dẹ́mà àti Lúùkù, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi Kí Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín Àdúrà Àti Ọpẹ́ Pọ́ọ̀lù àti Tìmótíù, àwọn ìránṣẹ́ Jésù Kírísítì, Sí gbogbo àwọn ènìyàn-mímọ́ nínú Kírísítì Jésù tí ó wà ní Fílípì, pẹ̀lú àwọn bíṣọ́ọ̀bù àti àwọn díákónì Oore-ọ̀fẹ́ sí yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Olúwa wa Jésù Kírísítì Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín Nínú gbogbo àdúrà mi fún-un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà, nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìyìn rere láti ọjọ́ kìn-ín-ni wá títí di ìsinsinyìí Ohun kan yìí ṣáà dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ Jésù Kírísítì Gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi láti ro èyí nípa gbogbo yín, nítorí tí mo fi yín sọ́kàn, bí mo tilẹ̀ wà nínú ìdè tàbí ìdáhùn ẹjọ́, àti ìfẹsẹmúlẹ̀ ìyìnrere, gbogbo yín jẹ́ alábàápín oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú mi Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jésù Kírísítì Èyí sì ni àdúrà mi pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti ṣíwájú síi nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè dà ohun tí ó dára jùlọ yàtọ̀ mọ̀, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ọjọ́ Kírísítì, tí ẹ sì kún fún èso òdodo tí ó ti ọ́dọ̀ Jésù Kírísítì wá—fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run Ǹjẹ́ èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀, ará, pé ohun tí ó ẹlẹ̀ sí mi já sí àtẹ̀gùn sí ìlọsíwájú ìyìnrere Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangban sí gbogbo àwọn ẹ̀sọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kírísítì Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni ẹ ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run síi pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kírísítì, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é Àwọn ti ìkẹ́yìn n fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a ó gbé mi dìde fún ìgbèjà ìyìn rere Ṣùgbọ́n àwọn ti ìṣáájú ẹ̀wẹ̀ ń fi ìlépa ara ẹni ń wàásù Kírísítì, kì í ṣe pẹ̀lú òótọ́ inú, wọn ń gbérò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi ni Ṣùgbọ́n ohun tí ó sa ṣe pàtàkì ni pé, bóyá a wàásù pẹ̀lú ètè tó dára tàbí èyí tí kò dára, a ṣsá ń wàásù Kírísítì Èyí sì ni ayọ̀ mi Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì máa yọ̀ Nítorí tí mo mọ̀ pé nípa àdúrà yín àti ìrànlọ́wọ́ tí Ẹ̀mí Jésù Kírísítì, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi yóò padà já sí ìtúsílẹ̀ mi Ó jẹ́ ìfojúsọ́nà àti ìrètí mi pé ojú kì yóò tì mí nínú ohunkóhun, ṣùgbọ́n èmi ó ní ìgboyà nísinsìnyìí bí ti ìgbà gbogbo pé ní yíyè, tàbí ní kíkú, a ó gbé ga lára mi Nítorí, níti èmi, láti wa láàyè jẹ́ Kírísítì, láti kú jẹ́ èrè Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì wà láàyè nínú ara, èyí yóò jásí èrè fún iṣẹ́ mi Síbẹ̀, kíni èmí yóò yàn Èmi kò mọ̀ Mo wà ní agbede méjì Mo fẹ́ràn láti wà pẹ̀lú Kírísítì, èyí tí ó dára jùlọ Ṣùgbọ́n ó ṣe iyebíye fún yín kí èmi kí ó wà nínú ara Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́, kí ìbádàpọ̀ mi pẹ̀lú yín lẹ́ẹ̀kan si le ru ayọ̀ yín sókè nínú Kírísítì nítorí mi Ohun tó wù kí ó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí iṣẹ́ yín wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyìnrere Kírísítì pé yálà bí mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin sì jùmọ̀ n jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìyìn rere, pẹ̀lú ọkàn kan láìsí ìbẹ̀rẹ̀ àwọn tí ó dojúkọ yin lọ́nà kanna Èyí sì jẹ́ àmì fún wọn pé a ó pa wọ́n run, a ó sì gbà yín là —èyí tí Ọlọ́run yí ó ṣe Nítorí a ti fi fún yín nítorí Kírísítì, kì í ṣe láti gbàgbọ́ nínú rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú Nípa níní ìjàkadì kan náà tí ẹ̀yin ti rí tí èmi là kọjá, ti ẹ sì gbọ́ nísinsinyìí pé mo sì wà nínú rẹ̀ Kọ́ Ìwà Ìrẹ̀lẹ̀ Kírisítì Bí ìwọ bá ní ìmúlọ́kànlé nítorí pé ìwọ wà ní ìsọ̀kan pẹ̀lú Kírísítì, bi ìtùnú kan bá wà nínú ìfẹ́ rẹ̀, bí ìdàpọ̀ Ẹ̀mí kan bá wà, bí ìyọ́nú àti ìṣeun bá wà, síbẹ̀ ẹ mú ayọ̀ mi kún nínú ìsọ̀kan yín, níní ìfẹ́ kan náà, wíwà ní ẹ̀mí kan náà àti ète kan náà Ẹ má ṣe ohunkóhun nínú ìlépa-ara tàbí ògo asán, sùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí olúkúlùkù ro àwọn ẹlòmíràn sí ẹni ti ó sàn ju òun lọ Kí olúkúlùkù yín má ṣe ro ohun ti ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ti ẹlòmíràn pẹ̀lú Ìṣe yín gbọdọ̀ dàbí ti Kírísítì Jésù Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run, kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba Ṣùgbọ́n kò ka ara rẹ̀ sí ohunkóhun, ó sì gba àbùdá ìránṣẹ́, a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, Ó sì tẹríba títí di ojú ikú, àní ikú àgbélébùú Nítorí náà, Ọlọ́run ti gbé e ga sí ìpele tí ó ga jùlọ, ó sì ti fi orúkọ kan ti ó borí gbogbo orúkọ Pé ni orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa wólẹ̀, ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé, Àti pé kí gbogbo ahọ́n jẹ́wọ́ pé, Jésù Kírísítì ni Olúwa, fún ògo Ọlọ́run Baba Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́ràn nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárin yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, Nítorí pé Ọlọ́run ni ó n ṣiṣẹ́ nínú yín, láti fẹ́ àti láti ṣiṣẹ́ fún ète rere rẹ̀ Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí kíkùn àti ìjiyàn Kí ẹ̀yin lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti oníwà mímọ́, mọ Ọlọ́run, aláìlábàwọ́n, láàrin oníwà wíwọ́ àti alárèékérekè orílẹ̀-èdè láàrin àwọn ẹni tí a ń rí yín bí ìmọ́lẹ̀ ní ayé Bí ẹ sì se di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kírísítì pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán Ṣùgbọ́n, bí a tilẹ̀ ń dà mí bí ọtí-ìrúbọ sórí ẹbọ iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, inú mi dùn, mo sì ń bá gbogbo yín yọ̀ pẹ̀lú Bákan náà ni kí ẹ̀yin máa yọ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀ pẹ̀lú Mo ni ìrètí nínú Jésù Olúwa, láti rán Tìmótíù sí yín ni àìpẹ́ yìí, kí èmi pẹ̀lú lè ni ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí mo bá gbúrò yín Nítorí èmi kò ni ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀, tí yóò máa fi tinútinú ṣe àníyan yín Nítorí gbogbo wọn ni ó tọ́jú nǹkan ti ara wọn, kì í ṣe àwọn nǹkan ti Jésù Kírísítì Ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ̀ pé Timotiu pedegé, gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́dọ̀ baba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ti ń bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀, nínú iṣẹ́ ìyìnrere Nítorí náà, mo ní ìrètí láti rán sí yín ní àìpẹ́ tí mo bá wòye bí yóò ti rí fún mi Ṣùgbọ́n mo ní gbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, pé èmi tikarami pẹ̀lú yóò wá ní àìpẹ́ Mo kà á sí pé n kò lè ṣàìrán Epáfíródítù arákùnrin mi sí yín, àti olùbá ṣiṣẹ́ pọ̀ mi, àti ọmọ-ogun ẹlẹ́gbẹ́ mi, ìránṣẹ́ yín pẹ̀lú, tí ẹ rán láti ṣè ránṣẹ́ fún mi nínú àìní mi Nítorí tí ọkàn rẹ̀ fà sí gbogbo yín, ó sì kún fún ìbànújẹ́, nítorí tí ẹ̀yin gbọ́ pé ó ṣe àìsàn Nítòótọ́ ni ó ti ṣe àìsàn títí dé ojú ikú, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ṣàánú fún un kì í sì í ṣe fún òun nìkan, ṣùgbọ́n fún èmi pẹ̀lú kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lórí ìbànújẹ́ Nítorí náà ni mo ṣe ní ìtara láti rán an, pé nígbà tí ẹ̀yin bá sì tún rí i, kí ẹ̀yin lè yọ̀ àti kí ìkáyà sókè mi lè dínkù Nítorí náà, ẹ fi ayọ̀ púpọ̀ gbà á nínú Olúwa kí ẹ sì máa bu ọlá fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ Nítorí iṣẹ́ Kírísítì ni ó ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú, tí ó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wé wu, láti mu àìtó iṣẹ́ ìsìn yín sí mi kún Kò Sí Ìgbẹ́kẹ̀lé Ẹlẹ́ran Ara Ní àkótán ará, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa wa Kì í ṣe ìnira fún mi láti kọ̀wé ohun kan náà sí yín, ṣùgbọ́n fún yín ó jẹ́ àìléwu Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn ajá, ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́-búburú, ẹ sì kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn onílà Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kírísítì Jésù, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran ara Bí èmi tìkárami pẹ̀lú ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara, tèmi tilẹ̀ pọ̀ Ẹnii tí a kọ nílà ní ijọ́ kẹjọ, láti inú kùkùté Ísírẹ́lì wá, láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Hébérù láti inú Hébérù wá nítorí, ní ti òfin Farisí ni èmi Ní ti ìtara, èmi ń ṣe inúnibínu sí ìjọ ní ti òdodo tí ó wà nínú òfin, mo jẹ́ aláìlẹ́gàn Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kírísítì Nítòótọ́ láìṣe àní-àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kírísítì Jésù Olúwa mi nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní láárí, kí èmi lè jèrè Kírísítì, Kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkarami, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kírísítì, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ Kí èmi lè mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábàápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá faramọ́ ọn nínú ikú rẹ̀ Bí ó lè ṣe é ṣe kí èmi lè ní àjíǹde kúrò nínú òkú Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti tẹ̀ ẹ́ ná, tàbí mo ti di pípé ṣùgbọ́n èmi ń lépa ǹṣó, bí ọwọ́ mi yóò lè tẹ èrè náà nítorí èyí tí a ti dì mí mú pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ Kírísítì Jésù wá Ará, èmi kò kara mi sí ẹni ti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́ ná Ṣùgbọ́n ohun kan yìí ni èmi ń ṣe, èmi ń gbàgbé àwọn nǹkan tí ó ti kọjá Lẹ́yìn náà mo ń nàgà wo àwọn nǹkan tí ó wà níwáju Èmi ń lépa láti dé òpin aré-ìje náà fún èrè ìpè gíga Ọlọ́run nínú Kírísítì Jésù Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a dàgbà nípa ti ẹ̀mí ni èrò yìí bí ẹ̀yin bá sì ní èrò mìíràn nínú ohunkóhun, èyí náà pẹ̀lú ni Ọlọ́run yóò fi hàn yín Kìkì pé, ibi tí a ti dé ná, ẹ jẹ́ kí a máa rìn ní ojú-ọ̀nà kan náà, kí a ni èrò kan náà Ará, ẹ jùmọ̀ ṣe àfarawé mi, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn tí ń rìn bẹ́ẹ̀, àní bí ẹ ti ní wa fún àpẹẹrẹ Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ń rìn, nípasẹ̀ àwọn ẹni tí mo ti ń wí fún yín nígbàkúùgbà, àní, tí mo sì ń sọkún bí mo ti ń wí fún yín nísinsinyìí, pé, ọ̀ta àgbélébùú Kírísítì ni wọ́n Ìgbẹ̀yìn wọn ni ìparun, ikùn wọn sì ni Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń ṣògo nínú ìtìjú wọn, àwọn ẹni tí ń tọ́jú ohun ti ayé Nítorí ìlú-ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ lọ́run láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jésù Kírísítì Olúwa Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀ Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìyànjú Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ti mo sì ń ṣàfẹ́rí gidigidi, ayọ̀ àti adé mi, ẹ dúró ṣinṣin bẹ́ẹ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olùfẹ́ mi Èmi ń bẹ̀ Éúódíà, mo sì ń bẹ Síńtíkè, kí wọn ní inú kan náà nínú Olúwa Mo sì bẹ̀ ọ́ pẹ̀lú bí alájọrù àjàgà mi tòótọ́, ran àwọn obìnrin wọ̀nyí lọ́wọ́, nítorí wọn bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ nínú ìyìn rere, àti Kílẹ́mẹ́ńtì pẹ̀lú, àti àwọn olùbá-ṣiṣẹ́ mi yòókù pẹ̀lú, orúkọ àwọn tí ń bẹ nínú ìwé ìyè Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo mo sì tún wí pé Ẹ máa yọ̀ Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòòsí Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín máa nínú Kírísítì Jésù Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òótọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé, níṣinṣinyìí, ẹ̀yin tún ti sọjí nínú àníyàn ọkàn yín sí mi, nítòótọ́ ọkàn yín ń fà mọ́ mi ṣùgbọ́n ẹ kò ní àǹfààní tó Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní nítorí pé ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀ Mo mọ̀ bí a ti ṣe ń rẹ ara sílẹ̀, mo sì mọ̀ bí a ti ń di púpọ̀ ni ohunkóhun àti ní ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó àti láti wà ni àìjẹ, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kírísítì ẹni ti ń fi agbára fún mi Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábàápín nínú ìpọ́njú mi Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Fílípì, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìyìn rere, nígbà tí mo kúrò ni Makedóníà, kò sí Ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábàápín ní ti gbígbà àti fífúnni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo Nítorí ní Tẹsalóníkà ẹ̀yin fi nǹkan ránṣẹ́, lẹ́ẹ̀kan fún àìní mi Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín Ṣùgbọ́n mo ní ohun gbogbo, mo sì ti di púpọ̀ mo sì kún nígbà ti mo tí gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Ẹ́páfíródítù tí a ti rán wá lọ́dọ̀ yín, ọrẹ olóòórún dídùn, ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà, tì í ṣe inú dídùn gidigidi sí Ọlọ́run Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kírísítì Jésù Ṣùgbọ́n ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba wa láé àti láéláé Àmín Ẹ kí olukùlùkù ènìyàn-mímọ́ nínú Kírísítì Jésù Àwọn ará tí ó wà pẹ̀lú mi kí yín Gbogbo àwọn ènìyàn-mímọ́ kí yín, pàápàá àwọn tí ń ṣe ti agbo ilé Késárì Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín Àmín Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ Èròngbà àti kókó ọ̀rọ̀ Àwọn òwe ti Sólómónì, ọmọ Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́ Láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Láti ní ẹ̀kọ́ àti gbé ìgbé ayé ìkíyèsára, láti ṣe ohun tí ó tọ́, àti òdodo tí ó sì dára láti fún onírẹ̀lẹ̀ ní ìkíyèsára ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe Jẹ́ kí Ọlọgbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀, sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtàn-dòwe, àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn Ọlọgbọ́n Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́ Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá ọ̀ rẹ sílẹ̀ Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòrùn dídùn lórí rẹ àti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn Bí wọn bá wí pé, Tẹ̀lé wa kálọ jẹ́ ká ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ ká dá àwọn aláìlera kan lọ́nà Jẹ́ ká gbé wọn mì láàyè, bí ibojì òkú, àti lódindi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò A ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí a ó sì fi ìkógún kún inú ilé wa Dara pọ̀ mọ́ wa, a ó sì jọ powó sínú àpò kan náà Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ, má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ okùn de ẹyẹ, ní ìṣojú u gbó ẹyẹ! Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn Ara wọn ni wọ́n ń dá lóhùn Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́ yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ Ìkìlọ̀ láti má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀ Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópó ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrin ọjà Láàrin ọjà ni ó ti kígbe jáde Ní ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ́kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀ Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni, Ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yín kí n sì fi inú un mi hàn sí i yín Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo háwọ́ sí wọn, Níwọ̀n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi tí ẹ kò sì ní gba ìbáwí mi Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín N ó sẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle, Nígbà tí ìdàámú bá dé bá ọ bí ààjà, nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀ Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn wọn yóò farabalẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi Níwọ̀n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀ tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù Olúwa Níwọ̀n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi, Wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún Nítorí ìrìnkurìn àwọn aláìmọ́kan ni yóò pa wọ́n ìkáwọ́-gbera aláìgbọ́n ni yóò pa á run Ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láì sí ìbẹ̀rù ìpalára Àwọn Òwe Sólómónì Àwọn òwe Sólómónì Ọlọgbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́ Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú Olúwa kì í jẹ́ kí ebi máa pa Olódodo ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́ Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di talákà, ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra síṣẹ́ a máa sọni di ọlọ́rọ̀ Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ Ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ Ìbùkún ní ó máa ń kún orí Olódodo ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú Ìrántí Olódodo yóò jẹ́ ìbùkún ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun Ẹni oníwà títọ́ ń rìn láìléwu ṣùgbọ́n àsírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú Ẹni tí ń sẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn Aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun Ẹnu Olódodo jẹ́ oríṣun ìyè ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀ Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye ṣùgbọ́n kùmọ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun Ọrọ̀ àwọn Olódodo ni ìlú olódi wọn, ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní Èrè Olódodo ń mú ìyè wá fún wọn ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn sìnà Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́ ẹni tí ó sì ń báni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n Ètè Olódodo jẹ́ àṣàyan fàdákà ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn buburú kò níye lórí Ètè Olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye Ìbùkún Olúwa ń mú ọrọ̀ wá, kì í sìí fi ìdàámú sí i Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a Olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ, ṣùgbọ́n Olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́ Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá, ṣùgbọ́n a gé ojọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú Ìrètí Olódodo ni ayọ̀ ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn buburú já sí òfo Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún Olódodo, ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń se ibi A kì yóò fa Olódodo tu láéláé ṣùgbọ́n ènìyàn buburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀ Ẹnu Olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá, ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò Ètè Olódodo mọ ohun tí ó tọ́, ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ Olúwa kórìíra òṣùwọ̀n èké ṣùgbọ́n òṣùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀ Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìsòótọ́ wọn Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú ṣùgbọ́n òdodo a máa gba ni lọ́wọ́ ikú Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fàá lulẹ̀ Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là ṣùgbọ́n ìdẹkùn ètè búburú mú aláìsòótọ́ Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun gbogbo ohun tó ń fojú sọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já sófo A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀, ibi wá sórí ènìyàn búburú Aláìmọ̀ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ Olódodo sá àsálà Nígbà tí Olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀ nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan Nípaṣẹ̀ ìbùkún, Olódodo a gbé ìlú ga ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́ Olófòófó tú àsírí ìkọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àsírí mọ́ Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀ èdè ṣubú ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú Ẹni tí ó ṣe onídùúró fún ẹlòmíràn yóò jìyà dájúdájú, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onídùúró yóò wà láì léwu Obìnrin oníwà rere gba ìyìn ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóore ṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀ Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ ṣùgbọ́n ẹni tó fúrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú Olódodo tòótọ́ rí ìyè ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀ Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù Mọ èyí dájú pé ènìyàn búburú kì yóò lọ láì jìyà, ṣùgbọ́n àwọn Olódodo yóò lọ láì jìyà Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n Ìfẹ́ inú Olódodo yóò yọrí sí ohun rere ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura Àwọn ènìyàn a ṣépè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́ ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere ṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú ṣùgbọ́n Olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù Ẹni tí ó ń mú ìdàámú dé bá ìdílé rẹ̀ yóò jogún afẹ́fẹ́ lásán aláìgbọ́n yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún Ọlọgbọ́n Èṣo òdodo ni igi ìyè ẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ Ọlọgbọ́n Bí àwọn Olódodo bá gba ìpín wọn lórí ilẹ̀ ayé mélòó mélòó ni aláìwà bí Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n Ènìyàn rere gba ojú rere lọ́dọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n Olúwa kórìíra alárekérekè ènìyàn A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú ṣùgbọ́n a kò le è fa Olódodo tu Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí ìgbà tí inú egungun rẹ̀ jẹrà Ète àwọn Olódodo dára ṣùgbọ́n ìmúra ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn Olódodo gbà wọ́n là A sí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́ ṣùgbọ́n ilé Olódodo dúró ṣinṣin A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láì lóúnjẹ Ènìyàn rere ń ṣaájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò Àmọ́ ìwà tó dára jù tí ènìyàn búburú lè hù, ibi ni Ẹni tí ó bá dáko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásánlàsàn kò gbọ́n Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógún àwọn ènìyàn ìkà ṣùgbọ́n gbòǹgbò Olódodo ń gbilẹ̀ A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n Olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdàámú Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n Ọlọgbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́ṣẹ̀kẹṣẹ̀, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí tòótọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́ Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọgbọ́n ń mú ìwòsàn wá Ètè tí ń sòótọ́ yóò wà láéláé ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́ Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú ṣùgbọ̀n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀ Ibi kì í ṣubú lu Olódodo rárá ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn Olúwa kóìríra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn Olóòótọ́ Ènìyàn Olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jọba ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí sínsìnrú Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀ Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn sìnà Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀ Ní ọ̀nà àwọn Olódodo ni ìyè wà ní ọ̀nà náà ni àìkú wà Ọlọ́gbọ́n ọmọ pa àṣẹ baba rẹ̀ mọ́ ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò fetí sí ìbáwí Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn àwọn ohun rere ṣùgbọ́n, aláìsòótọ́ ní ìfẹ́ ọkàn láti inú ìwà ipá Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù-gbàù yóò parun Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkankan, ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́ Ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòótọ́ inú, ṣùgbọ́n ìwà búburú sí ẹlẹ́ṣẹ̀ nípò Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkankan ẹlòmííràn díbọ́n bí i talákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀ Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ ṣùgbọ́n talákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro, ṣùgbọ́n àtùpà ènìyàn búburú ni a pa kú Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn Owó tí a fi ọ̀nà èrú kó jọ yóò sí lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀ díẹ̀ yóò pọ̀ síi Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀ Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹkùn ikú Òye pípé ń mú ni rí ojú rere Ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìsòótọ́ kì í tọ́jọ́ Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀ Ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdàámú ṣùgbọ́n aṣojú olóòtọ́ mú ìwòsàn wá Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di talákà yóò sì rí ìtìjú, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá Ìfẹ́ tí a múṣẹ dùnmọ́ ọkàn ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo Ilẹ̀ ẹ talákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irè oko wá ṣùgbọ́n àìsòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa báa wí Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ wó o Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa , ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn Olúwa Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàsán fún ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóní ṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá Ẹlẹ́rìí tí ń sòótọ́ kì í tan ni ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá, ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn, nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀ Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà an wọn ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ asìwèrè ni ìtànjẹ Aláìgbọ́n ń ṣẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n láàrin àwọn olódodo ni a ti rí ojú rere Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀ kò sì sí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀ A ó pa ilé ènìyàn búburú run Ṣùgbọ́n àgọ́ Olódodo yóò máa gbèrú síi Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa já sí ikú Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìnín, ọkàn leè máa kérora ayọ̀ sì leè yọrí sí ìbànújẹ́ A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ Ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀ Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́ ṣùgbọ́n Olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbéṣẹ̀ rẹ̀ Ọlọgbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè, a sì kórìíra eléte ènìyàn Òpè jogún ìwà òmùgọ̀ ṣùgbọ́n a dé ọlọgbọ́n ní adé ìmọ̀ Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rere àti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo Kódà àwọn aládùúgbò o talákà kò fẹ́ràn rẹ̀ ṣùgbọ́n, Ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í sìnà Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbérò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́ Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni Ọrọ̀ Ọlọgbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn ṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá Ẹlẹ́rìí tí ó ṣòótọ́ gba ẹ̀mí là ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn Ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa ni ilé ìṣọ́ ààbò yóò sì tún jẹ́ ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀ Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ oríṣun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo Ọba, ṣùgbọ́n láì sí ìjòyè, Ọba á parun Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀, ṣùgbọ́n onínú fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara, ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀, kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóye kódà láàrin àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun Ododo a máa gbé orílẹ̀ èdè ga, ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ Ọba a máa ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ tí ó gbọ́n ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ wá sórí ìránṣẹ́ adójútini Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè Ahọ́n ọlọgbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde Ojú Olúwa wà níbi gbogbo, Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọgbọ́n Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀ ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ẹ lọ́rùn Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an, ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú Ikú àti ìparun sí sílẹ̀ níwájú Olúwa mélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn Ẹlẹ́gàn kórìíra ìbáwí kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n Inú dídùn máa ń mú kí ojú túká ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run Ọkàn olóye ń wá ìmọ̀ ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń fẹ́ ìwà òmùgọ̀ bí ẹní jẹun Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi, ṣùgbọ́n ọkàn tí ń dunnú a máa Jàṣè ṣáá Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wà ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà sàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀ ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà Ẹ̀gún dí ọ̀nà ọ̀lẹ ṣùgbọ́n pópónà tí ń dán ni ti àwọn dídúró ṣinṣin Ọlọgbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ọmọ kẹ́gàn baba rẹ̀ Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀ ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn ṣùgbọ́n a máa yege níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràwà Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó báa mu ọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀! Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọgbọ́n láti sọ kí ó má bá à sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú Olúwa fa ilé onígbéraga ya lulẹ̀, Ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó mọ́ láìyẹ̀ Olúwa kórìíra èrò ènìyàn búburú, Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wò ṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburú ṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn, ìròyìn ayọ̀ sì ń mú ìlera wá sínú egungun Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè, yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀, Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ síi Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n, Ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn Ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dà bí i pé ó dára lójú ara rẹ̀ Ṣùgbọ́n Olúwa ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́ Èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́ Kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀ mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà Nípaṣẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípaṣẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn, yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn-án bá a gbé ní àlàáfíà Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀ Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa inú síi ẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ gbé ẹ̀bi fún ara rẹ̀ Òdiwọ̀n àti òṣùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀ Àwọn ọba kórìírà ìwà àìtọ́ nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀ Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣòótọ́ ènìyàn tí ń sọ òtítọ́ ṣe iyebíye sí wọn Ìrànṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́ ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè ojú rere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ àti láti yan òye dípò o fàdákà! Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi, ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀ Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun, agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú, ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrin àwọn olùpọ́njú jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ire, ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú Òye jẹ́ oríṣun ìyè fún àwọn tí ó ní i, ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n Ọkàn ọlọgbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ gbèrú Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú Ìfẹ́-àti-jẹun alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún un nítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ ni Ènìyàn búburú ń pète ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni Aláyìídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀ olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn níyà Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀ ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú Ewú orí jẹ́ ògo ìgbé ayé òdodo ní í múni débẹ̀ Ó sàn láti jẹ́ oníṣùúrù ju ajagun ènìyàn lọ, ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun-gbàlú lọ A ṣẹ́ kèké dàsí ìṣẹ́po aṣọ, ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ sàn ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ, yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Iná ni a fi fọ́ Sílífà àti wúrà Ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú Ẹni tí ó fi talákà ṣe yẹ̀yẹ́ kórìíra ẹlẹ́dàá talákà náà ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ torí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà Ọmọ-Ọmọ ni adé orí arúgbó òbí sì ni ìyangàn àwọn ọmọ Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aláìgbọ́n, mélòó mélòó ni ètè tí ń parọ́ fún àwọn alákóso! Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ oògùn fún ẹni tí ó ń fún ni ohun gbogbo, ibikíbi tí ó bá tẹ̀ sí ni ó ń yege Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì níyà Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun ènìyàn olóye ju ọgọ́rùn ún pàsán lẹ́yìn aláìgbọ́n Oríkunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe, ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i Ó sàn kí ènìyàn pàdé béárì tí a ti kó lọ́mọ jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ire, ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi, Olúwa kóríra méjèèjì Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè níwọ̀n bí kò ti ní èròńgbà láti rí ọgbọ́n Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, Arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀ Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun Ènìyàn aláyìídáyidà ọkàn kì í gbèrú ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu Láti bí aláìgbọ́n lọmọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n Ọkàn tí ó túká jẹ́ ogún gidi ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ láti yí ìdájọ́ po Olóyè ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé Aláìgbọ́n ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀ tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ ènìyàn olóye sì máa ń ní ṣùúrù Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọgbọ́n bí ó bá dákẹ́ àti bí olóye bí ó bá fètèmétè Ènìyàn tí kò báni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀ ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye ṣùgbọn ó ní inú dídùn sí ṣíṣọ èrò tirẹ̀ Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jínjìn ṣùgbọ́n oríṣun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń ṣàn Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúṣáájú fún ènìyàn búburú tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀ Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀ ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́ ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹkùn fún ọkàn rẹ̀ Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn wọ́n ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí akínyẹmí ara Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀ arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun Orúkọ Olúwa , ilé ìṣọ́ agbára ni olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni Sáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́ òun náà ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀ Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀ etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀ Ẹ̀bùn máa ń sí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí Ẹni tí ó kọ́kọ́ rojọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àsírí gbogbo Ìbò dídì máa ń parí ìjà a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn Arákùnrin tí a ṣẹ̀ ṣòroó yípadà ju ìlú olódi lọ, ìjà sì dàbí ibodè ìlú olódi ńlá tí a ṣe Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó Ahọ́n ni agbára ìyè àti ikú, àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹẹ́ Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere, Ó sì gba ojú rere lọ́dọ̀ Olúwa Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú, Ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun Ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó sún mọ́ ni tímọ́ tímọ́ ju arákùnrin Ó sàn kí èèyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà Kò dára láti ní ìtara láì ní ìmọ̀ tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì sìnà Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run ṣíbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa Ọrọ̀ má a ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀ ṣùgbọ̀n ọ̀rẹ́ ẹ talákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀ Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láì jìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́ Ọ̀pọ̀ ń wá ojú rere Olórí gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́ Gbogbo ará ilé e talákà ni ó pa á tì mélòómélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un! Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀, kò tilẹ̀ rí wọn rárá Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀ ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọlá ńlá, mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jọba lórí ọmọ aládé Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní ṣùúrù fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá Ìbínú ọba dàbí kíke e kìnnìún, ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko Aláìgbọ́n ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀, Aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀sọ̀ọ̀rọ̀ òjò A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí ṣùgbọ́n aya olóye láti ọdọ̀ Olúwa ni Ọ̀lẹ ṣíṣẹ́ máa ń fa oorun sísùn fọnfọnfọn ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra Ẹni-kẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú Ẹni tí ó ṣáànú talákà, Olúwa ní ó yá yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú iparun un rẹ̀ Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀ bí ìwọ bá gbàá là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan síi Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́ ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ó sàn láti jẹ́ talákà ju òpùrọ́ lọ Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láì sí ewu Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀ Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ síi Ẹni tí ó já baba rẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde ó jẹ́ adójútini ọmọ Yéé tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ tí í mú ni ṣìnà ọmọ mi, ìwọ kì yóò sì sìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìmọ̀ Ajẹ́rìí tí ó bàjẹ́ máa ń kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́ ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mi A ti pèṣè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn àti pàṣán fún ẹ̀yìn aláìgbọ́n Èrè Ìwà Rere Tí Ọgbọ́n Ń Mú Wá Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ, tí o tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n tí o sì fi ọkàn rẹ sí òye, bí ìwọ sì pè fún ojú inú rẹ ríran tí o sì kígbe sókè fún òye bí ìwọ bá wá ṣàfẹ́rì rẹ̀ bí i fàdákà tí o sì wa kiri bí i fún ohun iyebíye tó fara sin Nígbà náà ni òye ẹ̀rù Olúwa yóò yé ọ, tí ó sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n, láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni aṣà fún àwọn tí ń rìn déédé, ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́ Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́ Nígbà náà ni òye ohun tí ó tọ̀nà tí ó sì dára, tí ó dára yóò yẹ́ ọ—gbogbo ọ̀nà dídara Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ Ara sísọ ni yóò dáàbò bò ọ Òye yóò sì pa ọ́ mọ́ Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà, tí ó kúrò ní ọ̀nà tààrà láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn, tí ó ní inú dídùn sí ibi ṣíṣe tí ó sì ń yayọ̀ nínú àyídáyidà ibi, ọ̀nà àwọn tí ó ṣe pálapàla tí wọ́n sì jẹ́ alérekérekè ní ọ̀nà wọn Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àgbèrè Obìnrin lọ́wọ́ aya oníwàkúwà àti àwọn ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀, tí ó ti fi ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú ọ̀nà rẹ̀ sì lọ sí ibi ẹ̀mí àwọn òkú Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà tàbí tí ó rí ipa ọ̀nà ìyè Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere kí o sì rìn ní ọ̀nà àwọn Olódodo Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náà àwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà lórí rẹ̀ ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náà a ó sì ya àwọn aláìsòótọ́ kúrò lórí rẹ̀ Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọ̀tí líle ẹnikẹ́ni tí ó bá sìnà nìpaṣẹ̀ wọn kò gbọ́n Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún ẹnikẹ́ni tí ó bá mú-un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́ Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan Ètè ọkàn ènìyàn dàbí, omi jínjìn ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń wí oore wọn jáde, ṣùgbọ́nn kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòótọ́ Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ Nígbà tí ọba bá jókóò sórí ilẹ̀ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀ Táni ó le è wí pé, Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́, mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀ Ìdíwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ Olúwa kórìíra méjèèjì Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀ nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran Olúwa ni ó dá méjèèjì Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di talákà má ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ Kò dára, kò dára ní ẹni tó ra ọjà máa ń wí nígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán, yóò máa yangàn bí òun tí ṣe rí i rà sí Góòlù wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà ẹ̀rú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn ṣùgbọ́n, a yọrí sí bi ẹnu tí ó kún fún èèpẹ̀ Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn bí o bá ń jagun, gba ìtọ́ṣọ́nà Olófòófó dalẹ̀ àsírí nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ jù Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri Ogún tí a kó jọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín Má ṣe wí pé, N ó ṣẹ̀ṣan àṣìṣe rẹ yìí fún ọ Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là Olúwa kórìíra òdiwọ̀n èké Òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn Olúwa ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni Ìdẹkùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò Ọlọgbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n Àtùpà Olúwa ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́, nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu Ògo ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn jẹ́ ewú orí ni iyì arúgbó Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ, pàsán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú Ìṣúra Ẹni Tí Ó Gbọ́n Ọkàn ọba ń bẹ lọ́wọ́ Olúwa a máa darí rẹ̀ lọ ibi tí ó fẹ́ bí ipa omi Gbogbo ọ̀nà ènìyàn dàbí i pé ó dára lójú rẹ̀ ṣùgbọ́n, Olúwa ló ń díwọ̀n ọkàn Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí Olúwa ju ẹbọ lọ Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga, ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni! Ètè àwọn olóye já sí èrè bí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá Ìṣúra tí a kójọ nípaṣẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́ jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹkùn ikú Ìwà ipá àwọn ènìyàn búburú yóò wọ́ wọn lọ, nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́ Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́ Ó sàn láti máa gbé ní kọ̀rọ̀ orí òrùlé ju láti ṣe àjọpín ilé pẹ̀lú aya oníjà Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibi aládùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn, òpè a máa kọ́gbọ́n Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburú ó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú, òun tìkárarẹ̀ yóò ké pẹ̀lú ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́ Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò àti owó-àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá, dẹ́kun ìbínú líle Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́ ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye, yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di talákà ẹni tí ó fẹ́ ọtí-wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀ Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó-ìràpadà fún olódodo, àti olùrékọjá fún ẹni dídúró-ṣinṣin Ó sàn láti jókòó ní ihà ju pẹ̀lú oníjà obìnrin àti òṣónú lọ Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n ènìyàn aṣiwèrè jẹ ẹ́ run Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè, òdodo, àti ọlá Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára, ó sì bi ibi-gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́, ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu Agbéraga àti alágídí ènìyàan ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀, tí ń hùwà nínú àdábọwọ́ ìgbéraga Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe Ó ń fi ìlara ṣojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́ ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró Ẹbọ ènìyàn búburú, ìríra ni mélòómélòó ni nígbà tí ó mú un wá pẹ̀lú èrò ìwà-ibi Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́, yóò dúró Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le ṣùgbọ́n ẹni ìdúró-ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́ Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye, tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú Olúwa A ń múra ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun ṣùgbọ́n ìṣẹ́gun jẹ́ ti Olúwa Orúkọ Rere Sàn Ju Ọrọ̀ Lọ Yíyan orúkọ rere ṣàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ, àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọ pọ̀ Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó ṣé ara rẹ̀ mọ́ ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n níyà Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè Ègún àti ìdẹkun ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀ nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀ Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbésè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká aṣán ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun Ẹni tí ó fẹ́ ìwà-funfun ti àyà, tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ Ojú Olúwa pa ìmọ̀ mọ́, ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò Ọ̀lẹ wí pé, Kìnnìún ń bẹ lóde! Ó pa mí ní ìgboro! Ẹnu àwọn Àṣẹ́wó obìnrín, ihò jínjìn ni ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀ Àyà ọmọdé ni ìwà-wèrè dì sí ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ Ẹni tó ń ni talákà lára láti ní ọrọ̀, tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ, yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn Dẹtí rẹ sílẹ̀, kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ nígbà tí a sì pèṣè wọn tán ní ètè rẹ Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà níti Olúwa , èmi fi hàn ọ́ lónìí, àní fún ọ Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradára sí ọ níti ìmọ̀ràn àti níti ẹ̀kọ́, Kí ó lè mú ọ mọ dídájú ọ̀rọ̀ òtítọ́ kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́ fún àwọn tí ó rán ọ Má ṣe ja talákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ talákà bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè Nítorí Olúwa yóò gbéjà wọn, yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà Má ṣe bá oníbìínu ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́ má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀wọ́, tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi ṣan, nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹní rẹ kúrò lábẹ́ rẹ Má ṣe yẹ ààlà ilẹ ìgbàanì, tí àwọn baba rẹ ti pa Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀ Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ Ohun Àdídùn Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun, kíyèsí ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun, bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn Má ṣe fẹ́ oúnjẹ-dídùn rẹ̀ nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀ síwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́-apá fún ara rẹ̀, ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run Má ṣe jẹ oúnjẹ olójú búburú, bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ-dídùn rẹ̀ Nítorí pé bí ẹni tí ń sírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí Má a jẹ, kí o sì máa mu, ni ó ń wí fún ọ ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde, ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ Má ṣe sí ààlà àtijọ́ kúrò má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára yóò gba ìjà wọn jà sí ọ Fi àyà sí ẹ̀kọ́, àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀ Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé, nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú Bí ìwọ fi pàṣán nà án, ìwọ ó sì gbà ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run-àpáàdì Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n, ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́ Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù Olúwa , ní ọjọ́ gbogbo Nítorí pé ìkẹyìn ń bẹ nítòótọ́ ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò Gbọ́, ìwọ ọmọ mi, kí o sì gbọ́n, kí o sì máa tọ́ àyà rẹ sí ọ̀nà títọ́ Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun Nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di talákà ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ, má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́, àti òye Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n, yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀ Jẹ́ kí bàbá rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀, sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn Ọmọ mi, fi àyà rẹ fún mi, kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ ní inú-dídùn sí ọ̀nà mi Nítorí pé panṣágà-obìnrin ọ̀gbun jínjìn ni àti àjèjì-obìnrin kànga híhá ni Òun á sì ba ní bùba bí olè, a sì sọ àwọn olùrékọjá di púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn Ta ni ó ni òsì Ta ni ó ni ìbànújẹ́ Ta ni ó ni ìjà Ta ni ó ni aṣọ̀ Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí-wáìnì àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò Ìwọ má ṣe wò ọtí-wáìnì nígbà tí ó pọ́n, nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago, tí a gbé e mì, tí ó ń dùn Níkẹyìn òun á bunisán bí ejò, a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀ Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin, àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ àyídáyidà Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárin òkun, tàbí ẹni tí ó dúbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀ Ìwọ ó sì wí pé, Wọ́n lù mí kò dùn mí wọ́n lù mí, èmi kò sì mọ̀ nígbàwo ni èmi ó jí Èmi ó tún máa wá òmíràn láti mu Àwọn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n Mìíràn Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́ Nítorí ọkàn wọn ń gbérò ohun búburú, ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀ Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́ nípa òye sì ni ó ti fìdí múlẹ̀ Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀, ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára síi Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà nínú ìsẹ́gún ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀ Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí Ẹni tí ń pète ibi ni a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó! Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ síbi ikú là fa àwọn tó ń ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n lọ síbi ìparun padà Bí ìwọ bá wí pé, Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkankan nípa èyí, ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsíi Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́ Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára, oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ ìrètí rẹ kì yóò sì já sófo Má ṣe ba ní ibùba bí i arúfin dé ilé Olódodo, má ṣe kó ibùgbé è rẹ̀ lọ Nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà méje, yóò tún padà dìde ṣáá ni, ṣùgbọ́n ìdàámú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀ Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínú yóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi tàbí jowú àwọn ènìyàn búburú, nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájú a ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi, má sì ṣe dara pọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn, ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n láti ṣe ojúṣàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, Ìwọ lo jàre àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì kọ̀ ọ́ Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi, ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn Ìdáhùn òtítọ́ ó dàbí ìfẹnu-koni-ní-ẹnu Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládúgbò rẹ láìnídìí, tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ Má ṣe wí pé, Mà á ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ, mo kọjá níbi oko aláìgbọ́n ènìyàn ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo, koríko ti gba gbogbo oko náà Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsí mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi Òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè àti àìní bí olè Àwọn Òwe Mìíràn Ti Sólómónì Wọ̀nyí ni àwọn òwé mìíràn tí Sólómónì pa, tí àwọn ọkùnrin Hẹsikáyà ọba Júdà dà kọ Ògo Olúwa ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́ láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jìn bẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà ohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípaṣẹ̀ òdodo Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba, má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrin àwọn ènìyàn pàtàkì Ó sàn kí ó wí fún ọ pé, Gòkè wá síhìn ín ju wí pé kí ó dójú tì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn bí aládùúgbò rẹ bá dójú tì ọ́ Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ, má ṣe tú àsírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ, àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójú tì ọ́ orúkọ burúkú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ ó dàbí èṣo wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀ Bí títutù òjò yìnyín ní àsíkò ìkórè ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtọ́ sí àwọn tí ó rán an ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láì sí òjò ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni Nípa ṣùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba bí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo tàbí kí ó máa lọ ṣíbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ Bí àdá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀ Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹṣẹ̀ tí ó rọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdàámú Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú, tàbí iyọ̀ tí a fi ra ojú egbò ọgbẹ́ tàbí bí ọtí kíkan tí a dà sórí sódà ní ẹni tí ń kọ orin sí ọkàn tí ó bàjẹ́ Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ bí òrùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí Olúwa yóò sì san ọẹ̀san rẹ̀ fún ọ Bí afẹ́fẹ́ gúṣù ti í mú òjò wá, bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùlé ju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀ Bí omi tútù sí ẹni tí òrùngbẹ ń gbẹ ni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kanga tí omi rẹ̀ bàjẹ́ ni olódodo tí ó fi àyè gba ènìyàn búburú Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù, bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́nni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni Bí ìlú tí odi rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu Bí òjò dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórè ọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn Bí ológoṣẹ́ tí ń sí kiri tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń rá bàbà Èpè kò le è mọ́ ẹni tí kò ṣiṣẹ́ èpè Èpè kì í jani bí a kò bá ṣiṣẹ́ èpè Lagbà fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀ Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀ Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipá ni kí a ránṣẹ́ nípaṣẹ̀ aṣiwèrè Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodiro ni òwe lẹ́nu àṣiwèrè Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títa ni fífún aláìgbọ́n ní ọlá Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtí ni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ẹni tí ó gba aṣiwèrè síṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀ Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ Ọ̀lẹ wí pé Kìnnìún wà lójú ọ̀nà kìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà Bí ilẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀ Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ, ó lẹ débi pé kò le è mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀ Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀, ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọgbọ́n Bí ènìyàn tí ó di ajá ní etí mú ni ẹni tí ń kọjá lọ tí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀ Bí i asínwín ti ń ju ọfà àti ọfà tí ń ṣekú pani ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹ tí ó sì wí pé, Àwàdà lásán ni mo ń ṣe Láìsí igi, iná yóò kú láì sí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀ Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlè wọn a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sí akínyẹmí ara Bí èédú lára ìkòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu tí ó mú ṣáṣá pẹ̀lú ọkàn búburú Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àsírí ara rẹ̀ ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́ nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀ Ìkóríra rẹ le è farasin nípa ẹ̀tàn ṣùgbọ́n àsírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀ Bí ẹnikan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀ Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà, ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pani run Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ àní ẹlòmíràn, kì í ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo ṣùgbọ́n ìmúbínú un aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀ ṣùgbọ́n tani ó le è dúró níwájú owú Ìbániwí gbangba sàn ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ Ọgbẹ́ láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ṣùgbọ́n ọ̀tá máa ń fẹnu-koni-lẹ́nu púpọ̀ Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó ṣùgbọ́n òróòro gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀ ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀ Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó Ṣàkóso Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀, má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdàámú dé bá ọ ó sàn kí o jẹ́ aládúúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà síni Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pamọ́ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí kàkàkí ó dúró ó tẹ̀ṣíwájú, ó sì jìyà rẹ̀ Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjòjì fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oní ìṣekúṣe Bí ènìyàn kan ń kígbe e ṣúre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀ a ó kà á sí bí èpè Àyà tí ó máa ń jà dàbí ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀ dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kun tàbí bí ẹni tí ó gbá òróró Bí irin tí ń pọ́n irin mú bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èṣo rẹ̀ ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí Iná fún fàdákà iná ìlérú fún wúrà, ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó, fi ọmọ odó gún-un bí èlùbọ́ ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀ Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà bojú tó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí adé kì í sì í wà lórí títí láéláé Nígbà tí a bá kó koríko jọ láti orí òkè àwọn àgùntàn yóò pèṣè aṣọ fún ọ, àti ewúrẹ́ yóò pèṣè owó oko Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíkì ewúrẹ́ láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé e ṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún Nígbà tí orílẹ̀ èdè bá ní orí kunkun, àwọn ọba rẹ̀ a máa pọ̀ ṣùgbọ́n olóye àti onímọ̀ a máa pa òfin mọ́ ọba tí ó ni àwọn talákà lára dàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ẹ̀gbìn lọ Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibi ṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá Olúwa dáradára Ó sàn láti jẹ́ talákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójú ti baba rẹ̀ Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù ń kó o jọ fún ẹlòmìíràn, tí yóò ní àánú àwọn talákà Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin, kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburú yóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n talákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀ Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì í ṣe rere, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù Olúwa nígbà gbogbo ṣùgbọ́n ẹni tí ó ṣé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Béárì tí ń halẹ̀ ni ènìyàn búburú tí ń jọba lórí àwọn aláìlágbára Ọba tí ó jẹ gàba lórí ìlú láì gbàmọ̀ràn kò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra èrè ìjẹkújẹ yóò gbádùn ọjọ́ gígùn Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn yóò máa joró rẹ̀ títí ikú má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́ Ẹni tí ìrìn rẹ̀ kò ní àbùkù wà láìléwu ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ayípadà yóò ṣubú lójijì Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun aṣán yóò kún fún òsì Olóòótọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ, láìjìyà Ojúṣááj ú ṣíṣe kò dára ṣíbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan Ahun ń sáré àti là kò sì funra pé òsì dúró de òun Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojú rere síi nígbẹ̀yìn ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè tí ó sì wí pé Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ irú kan ni òun àti ẹni tí ń panírun Ọ̀kanjúà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò gbilẹ̀ Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu Ẹni tí ó ń fifún talákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún Nígbà tí ènìyàn búburú bá dórí ìjọba, àwọn ènìyàn a na pápá bora ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú bá ṣègbé, àwọn olódodo ń gbilẹ̀ síi Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀ nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀ ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá aṣẹ́wó kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́ Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini, ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládúgbò rẹ̀ ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀ Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹkùn rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀ Olódodo ń ṣaápọn nípa ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn tálákà, ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó kan ènìyàn búburú nínú irú rẹ̀ Àwọn Ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kòrí ẹni-dídúró-ṣinṣin wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹ̀nú rẹ̀ bínú ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu Bí olórí bá fetí sí irọ́, gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀ Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ talákà pẹ̀lú òtítọ́ ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdí múlẹ̀ nígbà gbogbo Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójú ti ìyá rẹ̀ Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀ ṣùgbọ́n Olódodo yóò rí ìṣubú wọn Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà Ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfín mọ́ A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́ bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi-ara-síi Njẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀ Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè, Onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀ ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì Ẹni tí ó ń ran olè lọ́wọ́ gan an ni ọ̀ta rẹ̀ O ń gbọ́ epe olóhun kò sì le è fọhùn Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹkùn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóṣo, ṣùgbọ́n láti ọdọ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo Olódodo kórìíra àwọn aláìsòótọ́ ènìyàn búburú kórìíra olódodo Àwọn Àǹfààní Ọgbọ́n Mìíràn Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ Nítorí wọn yóò fún ọ ní ọjọ́ gígùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí ó sì mú ọ̀rọ̀ wá fún ọ Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí síléètì àyà rẹ Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojú rere àti orúkọ rere ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ Jẹ́wọ́ rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ yóò sì ṣe àkóso ọ̀nà rẹ Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi Èyí yóò mú ìlera fún ara à rẹ àti okun fún àwọn egungun rẹ Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa , pẹ̀lú àkọ́so oko ò rẹ Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya àgbá rẹ yóò kún à kún wọ́ sílẹ̀ fún wáìnì tuntun Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa má si ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí, Nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀, ẹni tí ó tún ní òye síi Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ kò sí ohunkohun tí a lè fi wé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́ Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀ sì ni ọrọ̀ àti ọlá Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ìtura, òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ ti àlàáfíà Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbàá àwọn tí ó bá sì dìí mú yóò rí ìbùkún gbà Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀ nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipòo wọn Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní ìyà, àwọ̀sánmọ̀ sì ń sẹ ìrì Ọmọ mi pa ìdájọ́ tí ó yè kooro mọ́ àti ìmọ̀yàtọ̀, má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìṣéwu, ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀ Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀ má ṣe bẹ̀rù ìdàámú òjijì tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí, nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé, Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀ ó fún ọ lọ́lá nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ, ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ Má ṣe fẹ̀ṣùn kan ènìyàn láì-ní-ìdí nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀, Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyìídáyidà ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo Ó fi àwọn oníyẹ̀yẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ Ṣùgbọ́n ó fi oore ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀ ọlọ́gbọ́n jogún iyì Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbọ́n ni ó dójú tì Àwọn ọ̀rọ̀ Ágúrì ọmọ Jákè, ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Ítíélì, sí Ítíélì àti sí Úkálì Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn N kò ní òye ènìyàn Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́n tàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀ Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀ Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀ Sọ fún mi bí o bá mọ̀ Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù oun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́ Ohun méjì ni mo ń bèèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀, ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan, Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ kí ń sì wí pé, Ta ni Olúwa Tàbí kí ń di òtòsì kí ń sì jalè kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò ṣẹ́ èpè lé ọ Ìwọ yóò sì jìyà rẹ̀ Àwọn kan wá ṣépè fún àwọn baba wọn tí wọn kò sì ṣúre fún àwọn ìyá wọn Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọn ṣíbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn Àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo, tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga Àwọn ẹni tí eyín wọn jẹ́ idà Àwọn tí èrìgì wọn kún fún ọ̀bẹ láti jẹ àwọn talákà run kúrò ní ilẹ̀ ayé àwọn aláìní kúrò láàrin àwọn ọmọ ènìyàn Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì Múwá! Múwá! ní wọn ń ké Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé, mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, Ó tó Ibojì, inú tí ó yàgàn, ilẹ̀, tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé, àti iná, tí kì í wí láéláé pé, Ó tó! Ojú tí ń fi baba ṣẹ̀fẹ̀, tí ó kẹ́gàn ìgbọràn sí ìyá ẹyẹ àkálá ẹ̀bá odò ni yóò yọ ọ́, igún yóò mú un jẹ Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi, mẹ́rin tí kò yé mi Ipa idì ní òfuurufú ipa ejò lórí àpáta ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami òkun àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúndíá lọ́wọ́ Èyí ni ọ̀nà alágbérè obìnrin ó jẹun o sì nu ẹnu rẹ̀ ó sì wí pé, N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́ Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ile ayé ti ń wárìrì lábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín Ìránṣẹ́ tí ó di Ọba aláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ́ Obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọ ìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́ Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyé síbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi Àwọn èrà jẹ́ ẹ̀dá tí ó ní agbára díẹ̀ síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò Ehoro jẹ́ ẹ̀dá tí kò ní agbára púpọ̀ ṣíbẹ̀ wọ́n ń ṣe ilé wọn sí ibi ihò àpáta Eṣú kò ní ọba ṣíbẹ̀ wọ́n ń jáde lọ papọ̀ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ a lè fi ọwọ́ mú aláǹgbá ṣíbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba Àwọn ohun mẹ́ta ní n bẹ tí ń rìn rere, ohun mẹ́rin tí ń kọrí sí ibi rere, Kìnnìún, alágbára láàrin ẹranko tí kì í sá fún ohunkóhun Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́ àti òbúkọ, àti ọba pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láyìíká rẹ̀ Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga, tàbí tí o bá ti gbèrò ibi, da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ! Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wá tí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde bẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá Àwọn ọ̀rọ̀ ti Lémúélì ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀, tí ó jẹ́ pé mọ̀mọ́ rẹ̀ ló kọ ọ́ Ìwọ ọmọ mi, ìwọ ọmọ inú mi, ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ̀ mi Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin, okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lémúélì kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle Kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́ Ṣọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fún ra wọn fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní Ta ni ó le rí aya oníwà rere Ó níye lórí ju iyùn lọ ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ púpọ̀ nínú rẹ̀ kò sì sí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀ Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ Ó sa aṣọ irun àgùtàn olówùú àti ọ̀gbọ̀ Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀ àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ Ó kíyèsí oko kan, ó sì rà á nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin àjàrà rẹ̀ Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbáratagbára Apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́ Ó ríi pé òwò òun pé fìtílà rẹ̀ kì í sìí kú ní òru Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú ó la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn talákà ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní Nígbà tí òjò dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀ ẹwu dáradára àti eléṣè é àlùkò ni aṣọ rẹ̀ A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibòde ìlú níbi tí ó ń jókòó láàrin àwọn àgbà ìlú Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀ Ó ń bojú tó gbogbo ètò ilé rẹ̀ kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́ Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibòde ìlú Ọgbọ́n Ni Ó Ga Jùlọ Tẹ́tí, Ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba fetí sílẹ̀ kí o sì ní òye sí i Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro Nítorí náà má ṣe kọ ìkọ́ni mi sílẹ̀ Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí, mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kanṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi Ó kọ́ mi ó sì wí pé Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró, pa òfin mí mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè Gba ọgbọ́n, gba òye, Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹṣẹ̀ kúrò nínú rẹ̀ Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojú tó ọ Ọgbọ́n ni ó ga jù Nítorí náà gba ọgbọ́n Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ, Ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn Mo tọ́ ọ sọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà Nígbà tí o rìn, ìgbẹ́sẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́ nígbà tí o bá sáré, iwọ kì yóò kọsẹ̀ Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ tọ́jú u rẹ̀ dáradára Nítorí òun ni ìyè rẹ Má ṣe gbé ẹṣẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀ yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi, wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búrurú wọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà Ipa ọ̀nà Olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀ Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn Ju gbogbo nǹkan tó kù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́ Nítorí òun ni oríṣun ìyè, mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìṣọkúṣọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ Jẹ́ kí ojú ù rẹ máa wo iwájú, jẹ́ kí ìwo ojú ù rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sáá Kíyèsí ìrìn ẹṣẹ̀ rẹ sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan má ṣe yà sọ́tùn-ún tàbí ṣósì pa ẹṣẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi Ìkìlọ̀ Láti Yàgò Fún Àgbèrè Ọmọ mi, fiyè sí ọgbọ́n ọ̀n mi tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ àròjinlẹ̀ mi kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́ Nítorí ètè alágbèrè aṣẹ́wó obìnrin a máa ṣun oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín, ó korò ju òróòro lọ ó mú bí idà olójú méjì Ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú ìgbéṣẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú Kò tilẹ̀ ronú nípa ọ̀nà ìyè ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́ Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ tẹ́tí sí mi má ṣe yàgò kúrò nínú àwọn nǹkan tí mo sọ Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà síi dáadáa má ṣe súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo agbára rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn kí àwọn àjòjì ó má baà fi ọrọ̀ rẹ ṣara rindin kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀ Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora, nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán Ìwọ yóò wí pé, Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó! Ọkàn mi ṣe wá kóòríra ìbáwí! N kò gbọ́ràn sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu, tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátapáta ní àárin gbogbo àwùjọ ènìyàn Mu omi láti inú un kànga tìrẹ Omi tí ń ṣàn láti inú kànga rẹ Ó ha yẹ kí omi ìṣun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà àti odò tí ń sàn lọ sí àárin ọjà Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan, má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjòjì láéláé Ǹjẹ́, kí oríṣun rẹ di àbùkù fún kí ó sì yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ tẹ́ ọ lọ́rùn nígbà gbogbo jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ̀ máa fà ọ́ títí láéláé Ọmọ mi, èéṣe tí ìfẹ́ aṣẹ́wó fi ń fà ọ́ tí ìwọ sì ń dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò farasin rárá fún Olúwa Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀wò Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn okùn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀ dì í le kankan Yóò kú nítorí àìgba ẹ̀kọ́ ìwà òmùgọ̀ ara rẹ̀ ló mú kó ṣáko lọ Ìkìlọ̀ Láti Sọ́ra Fún Ìwà Òmùgọ̀ Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe oníduúró fún aládùúgbò rẹ bí ìwọ bá ti bọwọ́ ní ìlérí májẹ̀mu pẹ̀lú ẹlòmíràn Bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté, Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹ níwọ̀n bí o ti kó sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ bẹ aládùúgbò rẹ dáadáa Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́, tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo àgbọ̀nrín kúrò lọ́wọ́ ọdẹ, bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ Tọ èèrùn lọ, ìwọ ọ̀lẹ kíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n! Kò ní olùdarí, kò sí alábojútó tàbí ọba, síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ Oorun díẹ̀, Òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀ Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà àti àìní bí adigunjalè Ènìyàn kénìyàn àti ènìyàn búburú, tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri, tí ó ń sẹ́jú pàkòpàkò, ó ń fi ẹsẹ̀ ṣe àmì ó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe, tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀ ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀ Nítorí náà ìdààmú yóò dé báa ní ìsẹ́jú akàn yóò parun lójijì láì sí àtúnṣe Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra síi Ojú ìgbéraga, Ahọ́n tó ń parọ́ ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, ọkàn tí ń pète ohun búburú, ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà, Ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ ìyá kan Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́ má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀ Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùsọ́ rẹ nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀ Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ àtùpà, ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àti ìtọ́niṣọ́nà ti ìbáwí ni ọ̀nà sí ìyè yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin oníṣekúṣe kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn aya tí ń rin ìrìnkurìn Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ síi nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra, nítorí Aṣẹ́wó yóò sọ ọ́ di àkàrà lásánlàsàn ẹ̀mí rẹ gan an sì ni alágbérè ń dọdẹ Ǹjẹ́ ènìyàn ha le è gbé iná lé orí itan kí aṣọ rẹ̀ sì má jòó Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná Kí ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì má jóná Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láì jìyà Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á Ṣíbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbérè kò nírònú ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀, ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè, kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san Kò ní gba nǹkankan bí ohun ìtanràn yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó Ìkìlọ̀ Nítorí Àwọn Asẹ́wó Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun kọ wọ́n sí inú ọkàn rẹ Wí fún ọgbọ́n pé, Ìwọ ni arábìnrin mi, sì pe òye ní ìbátan rẹ wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè, kúrò lọ́wọ́ ìyàwó onírìnkurìn àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀ Ní ojú fèrèsé ilé è mi mo wo ìta láti ojú ù fèrèsé Mo rí i láàrin àwọn aláìmọ́kan mo sì kíyèsí láàrin àwọn ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbérè obìnrin náà, ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀, bí òkùnkùn ṣẹ ń bo ni lára Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀, ó múra bí aṣẹ́wó pẹ̀lú ètè búburú Ó dìí mú, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnu pẹ̀lú ojú dídín ó wí pé Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi Nítorí náà ni mo ṣe jáde wá pádé è rẹ mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ! Mo ti tẹ́ ibùṣùn mi pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Éjíbítì Mo ti fi nǹkan Olóòórùn dídùn sí ibùṣùn mi bí i míra, álóè àti kínámónì Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀ jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́! Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé ó ti lọ sí ìrìnàjò jínjìn Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́ kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn Kíákíá ni ó tẹ̀lé e bí i màlúù tí ń lọ sí odò ẹran bí àgbọ̀nrín tí ó fẹ́ kẹsẹ̀ bọ pàkúté títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀, bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn, Láì mọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi fọkàn sí nǹkan tí mo sọ Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀, tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀ Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààra sí iṣà òkú, tí ó lọ tààra sí àgbàlá ikú Ọgbọ́n Ń Fi Ìpè Sítapè Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ní ìkòríta, ní ó dúró Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú, ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn, Ẹ̀yin aláìmọ́kan, ẹ kọ́gbọ́n ẹ̀yin aláìgbọ́n, ẹ gba òye Tẹ́tí, nítorí mo ní àwọn ohun iyebíye láti sọ Mo ya ẹnu mi láti sọ àwọn ohun tí ó tọ̀nà, Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́, nítorí ètè mi kórìíra ibi Gbogbo ọrọ ẹnu mi ni ó tọ́, kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyídà níbẹ̀ Fún Olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀ Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà, ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn, Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù ìyùn lọ, kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fi wé e Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkóòríra ibi mo kóríra ìgbéraga àti agídí, ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi mo ní òye àti agbára Nípaṣẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ aládé ń ṣàkóso àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi àwọn tí ó sì wá mi rí mi Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà Ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo, ní ojú ọ̀nà òtítọ́, mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀ Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́ A ti yàn mí láti ayérayé, láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀ Nígbà tí kò tíì sí òkun, ni a ti bí mi nígbà tí kò tíì sí ìsun tí ó ní omi nínú kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn, ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi, kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀ tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn, nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi, Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfuurufú lókè tí ó sì fi oríṣun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹṣẹ̀, Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi òkun kí omi má baà kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀, àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́, mo ń yọ̀ nígbà gbobgbo níwájú rẹ̀ mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́ fetí sí ìtọ́ṣọ́nà mi kí o sì gbọ́n má ṣe pa á tì sápá kan Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetí sílẹ̀ sí mi, tí ń sọ́nà ní ẹnu ọ̀nà mi lójoojúmọ́, tí ń dúró ní ẹnu ọ̀nà mi Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè ó sì rí ojú rere gbà lọ́dọ̀ Olúwa Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára gbogbo ẹni tí ó kórira mi fẹ́ ikú Ìpè Ti Ọgbọ́n Àti Àìgbọ́n Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀, ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì ó ti fi ilé pọn tí ó ti fọ̀nà rokà ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀ ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè, láti ibi tí ó ga jù láàrin ìlú Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá! Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé Wá, ẹ wá fẹ́ oúnjẹ mi sì mu wáìnì tí mo ti pò pọ̀ Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè rìn ní ọ̀nà òye Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣebẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ Bá Ọlọgbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ kọ́ Ọlọgbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i kọ́ Olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀ Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ nípa Ẹni mímọ́ ni òye Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláì ní ìmọ̀ Ó jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀ lórí ìjòkó níbi tí ó ga jù láàrin ìlú, ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ, tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí! Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún Omi tí a jí mu dùn oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn! Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀, pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà, tí kò rìn ní pa ìmọ̀ràn àwọn ènìyàn búburú tàbí ti kò ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn pọ̀, tàbí ti kò si bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́ Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú Rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa àti nínú òfin Rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru Ó dàbí igi tí a gbìn sí eti odò tí ń ṣàn, tí ń so èso Rẹ̀ jáde ní àkókò Rẹ̀ tí ewé Rẹ̀ kì yóò Rẹ̀ Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere Kò rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú! Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo, ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé Sáàmù 10 Èé ha ti ṣe, Olúwa , tí ìwọ fi dúró ní òkè réré È ha ti ṣe tí ìwọ fi ara Rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú Nínú àrékérekè ènìyàn búburú ti ó gbérò ni kí a ti mú wọn, lí a mú-un nínú ìlànà tí o gbérò Ó ń fọ́nnu nínú ìfẹ́ inú ọkàn Rẹ̀ o bùkún olójúkòkòrò ó sì ń kẹ́gàn Olúwa Ènìyàn búburú kò lè rí i nínú ìgbéraga Rẹ̀ kò sí àyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò Rẹ̀ Ọ̀nà Rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo òun ń gbéraga, òfin Rẹ sì jìnnà sí i òun kẹ́gàn àwọn ọ̀ta Rẹ̀ O wí fún ara Rẹ̀, Kò si ohun tí ó le mì mí Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo èmi kò si ní ní wàhálà Ẹnu Rẹ̀ kún fún ẹ̀gàn àti irọ́ àti ìtànjẹ wàhálà àti ohun búburú wa lábẹ́ ahọ́n Rẹ̀ Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò ó gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀, ojú Rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn talákà ní ìkọ̀kọ̀ O lúgọ ní bùba nínú pàǹtí ó lúgọ ní bùba làti mú àwọn aláìní ìrànwọ́ ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n Rẹ̀ Àwọn ẹni ìpalára Rẹ̀ run, ó Rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀ kí talákà bá a le bọ́ sí ọwọ́ agbára Rẹ̀ Ó wí fún ara Rẹ̀, Ọlọ́run ti gbàgbé Ó pa ojú Rẹ̀ mọ́ òun kì yóò rí i láéláé Dìde, Olúwa ! Gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè, Ọlọ́run Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú Èeṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara Rẹ̀, Kò ní pé mí láti ṣe ìṣirò Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni o ri wàhálà àti ìrora Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ Rẹ talákà fara Rẹ̀ jin fún ọ Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi pèé láti wa sírò fún iwà ìkà Rẹ̀ tí a kò le è rí Olúwa ń jọba láé àti láéláé àwọn orílẹ̀ èdè yóò ti ilẹ̀ Rẹ̀ ṣègbé Ìwọ́ gbọ, Olúwa , ìfẹ́ àwọn tí a ni lára Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ ìgbe wọn, Láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìni baba àti àwọn ti a ni lára, kí ọkùnrin, tí ó wà ní àyé, kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́ Sáàmù 100 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa , gbogbo ayé Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa Ẹ wá ṣíwájú Rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa, kí ẹyin kí ó mọ̀ pé tirẹ̀ ni àwa Àwa ní ènìyàn Rẹ̀ àti àgùntàn pápá Rẹ̀ Ẹ lọ sí ẹnu ọ̀nà Rẹ̀ pẹlú ọpẹ́ àti sí àgbàlá Rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ Rẹ̀ Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore ìfẹ́ Rẹ̀ sì wà títí láé àti òtítọ́ Rẹ̀ títí dé gbogbo ayé Sáàmù 101 Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo sí ọ Olúwa , èmi yóò máa kọrin ìyìn Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́sẹ̀, ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi Èmi yóò máa rìn ní ilé mi pẹ̀lú àyà pípé Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi iṣẹ́ àwọn tí o yapa ni èmi kórìíra wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi Èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú Ẹnikẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnikejì Rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀, oun ní èmi yóò gé kúrò ẹni tí ó bá gbé ojú Rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà, òun ní èmi kì yóò faradà fún Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtọ́ lórí ilẹ̀, kí wọn kí ó le máa bá mi gbé ẹni tí o bá ń rìn ọ̀nà pípé òun ni yóò máa sìn mí Ẹni tí o bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi, kò sí ẹni tí ń ṣèké ti yóò dúró ní iwájú mi Ní ojojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa lẹ́nu mọ gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú kúrò ní ìlú Olúwa Sáàmù 102 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ Má ṣe pa ojú Rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú Dẹ etí Rẹ sí mi nígbà tí mo bá pè, dámi lóhùn kíákíá Nítorí tí ọjọ́ rú bí èéfin egungun mi sì jóná bí ààrò Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi Nítorí ohùn ìkérora mi, egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran ara mi Èmi dà bí ẹyẹ igún ni ijù èmi dàbí òwìwí ibi ahoro Èmi dìde èmí dàbí ẹyẹ lórí ilé Ní ọjọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta ológosẹ́ mi ń gàn mí àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi si da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omíjé Nítorí ìbínú ríru Rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀ Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́ èmi sì rọ bí koríko Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa , ni yóò dúró láéláé ìrántí Rẹ láti ìran dé ìran Ìwọ ó dìde ìwọ o sì ṣàánú fún Síónì, nítorí ìgbà àti ṣe ojú rere sí i àkókò náà ti dé Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ wọ́n sì káànú ẹrùpẹ̀ Rẹ Àwọn ayé yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa , gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo Rẹ Torí tí Olúwa yóò gbé Síónì ró, yóò farahàn nínú ògo Rẹ̀ Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní kì yóò si gan ẹ̀bẹ̀ wọn Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀, àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ Rẹ̀ wá láti ọ̀run wá ni ó bojúwo ayé, Láti gbọ́ ìrora ará túbú, lati tú àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀ Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ni Síónì àti ìyìn Rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti ìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa Ní ipa ọ̀nà mi, ó Rẹ agbára mi sílẹ̀, ó gé ọjọ́ mi kúrú Èmi sì wí pé Ọlọ́run mi, Má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi ọdún Rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpilẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọrun si jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn wọn yóò sì di àpatì Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí ṣíbẹ̀, ọdún Rẹ kò sì ni òpin Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Rẹ̀ yóò dúró ní iwájú Rẹ pẹ́ a o sì fi ẹsẹ̀ irú ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú Rẹ Sáàmù 103 Yin Olúwa , ìwọ ọkàn mi àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ Rẹ̀ mímọ́ Yin Olúwa , ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore Rẹ̀ Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ jìn ọ́ tí ó sì wo gbogbo àrùn Rẹ̀ sàn, Ẹni tí o ra ẹ̀mí Rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú ẹni tí o fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé, Ẹni tí o fi ohun dídara tẹ́ ọ lọ́rùn kí ìgbà èwe Rẹ̀ le di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí a nilára Ó fi ọ̀nà Rẹ̀ hàn fún Mósè, iṣẹ́ Rẹ̀ fun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Olúwa ni aláàánú àti olóore, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú Rẹ mọ́ láéláé Òun kì í ṣe sí wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa bẹ́ẹ̀ ni kì í san-án fún wa gẹ́gẹ́ bí àìṣedédé wa Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ Bí ìlà òòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀ òòrun bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa Bí bàbá ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ Rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ Nítorí tí ó mọ dídá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ Rẹ̀ dà bí koríko, ó gbilẹ̀ bí ìtànnà ewéko ìgbẹ́ Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí Rẹ̀, kò sì rántí ibùjókòó Rẹ̀ mọ́ Ṣùgbọ́n láti ayé rayé ni ìfẹ́ Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀, àti òdodo Rẹ̀ wà láti ọmọ dé ọmọ Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́ àti àwọn tí ó rántí òfin Rẹ̀ láti ṣe wọ́n Olúwa ti pèsè ìtẹ́ Rẹ̀ nínú ọ̀run, ìjọba Rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo Yin Olúwa , ẹ̀yin ańgẹ́lì Rẹ̀ tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mọ́ Yin Olúwa , ẹ̀yin ogun ọ̀run Rẹ̀ gbogbo, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ Yin Olúwa , gbogbo iṣẹ́ Rẹ̀ ní ibi gbogbo ìjọba Rẹ̀ Yin Olúwa , ìwọ ọkàn mi Sáàmù 104 Yin Olúwa , ìwọ ọkàn mi Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ ọlá àti ọlá ńláni ìwọ wọ̀ ní aṣọ Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣọ ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi-àjà ìyẹ̀wù Rẹ Ìwọ ti ó ṣe àwọ̀sánmọ̀ ni kẹ̀kẹ́-ogun Rẹ ìwọ tí ó ń rìn lórí àpá ìyẹ́ afẹ́fẹ́ Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ Rẹ, Ọ̀wọ́ iná ni àwọn olùránsẹ́ Rẹ O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀ tí a kò le è mi láéláé Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí Rẹ ni àwọn omi lọ, nípa ohùn àrá Rẹ ni wọ́n sálọ Wọn ṣàn kọjá lórí àwọn òkè, wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀, sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn Ìwọ gbé òpin tí wọn kò le kọjá Rẹ̀ kálẹ̀ láéláé ní wọ́n kò ní lé bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn àfonífojì tí ó ń ṣàn láàrin àwọn òkè Wọn fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òùngbẹ wọn Àwọn ẹyẹ ojú òfurufu tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi wọn ń kọrin láàrin àwọn ẹ̀ka Ó bú omi rìn àwọn òkè láti iyẹ̀wù Rẹ̀ wá a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èṣo iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ àti àwọn ewébẹ fún ènìyàn láti lò kí ó le mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀, òróró láti mú ojú Rẹ̀ tan, àti àkàrà láti ra ọkàn Rẹ̀ padà Àwọn igi Olúwa ni a bomi rin dáradára, Kédárì tí Lébánónì tí ó gbìn Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn bí ó se tí àkọ̀ ni, orí igi páìnì ni ilé Rẹ̀ Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó àti àwọn àlàpà jẹ ààbò fún àwọn ehoro Òsúpá jẹ àmì fún àkókò òòrùn sì mọ̀ ìgbà tí yóò wọ̀ Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru, nínú èyí tí gbogbo ẹ̀ranko igbó ń rìn kiri Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Òòrùn ràn, wọn sì kó ara wọn jọ, wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ìhò wọn Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn, àti sí làálàá Rẹ̀ títí di àṣálẹ́ Iṣẹ́ Rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa ! Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá a Rẹ Bẹ́ẹ̀ ni òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú, tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìṣàlẹ̀ láìníye ohun alàyè tí tóbi àti kékeré Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn, àti Léfíàtanì, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú Rẹ̀ Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́ láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò Rẹ̀ Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn, wọn yóò kó o jọ nígbà tí ìwọ bá là ọwọ Rẹ̀, a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere Nígbà tí ìwọ bá pa ojú Rẹ mọ́ ara kò rọ̀ wọ́n nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ, wọn ó kú, wọn o sì padà sí erùpẹ̀ Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí Rẹ, ní a dá wọn, ìwọ sì tún ojú ayé ṣe Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ Rẹ̀ Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì, ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín Ní gbogbo ayé mí ní ń ó kọrin sí Olúwa èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ ọ lọ́rùn bí mo tí ń yọ̀ nínú Olúwa Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́sẹ̀ kúrò láyé kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́ Yin Olúwa , ìwọ ọkàn mi Yin Olúwa Sáàmù 105 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa , ké pe orukọ Rẹ̀ Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrin àwọn orílẹ̀ èdè Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i sọ ti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ gbogbo Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ Rẹ̀ Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀ Wá Olúwa àti ipá Rẹ̀ wa ojú Rẹ̀ nígbà gbogbo Rantí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe, ìyanu Rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ, Ẹ̀yin ìran Ábúráhámù ìránṣẹ́ Rẹ̀, ẹ̀yin ọmọkùnrin Jákọ́bù, àyànfẹ́ Rẹ̀ Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa ìdájọ́ Rẹ̀ wà ní gbogbo ayé Ó rántí májẹ̀mú Rẹ̀ láéláé, ọ̀rọ̀ tí ó páláṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran Májẹ̀mu tí ó ṣe pẹ̀lú Ábúráhámù, àti ìbúra tí ó búra fún Ísáákì Ó fi da Jákọ́bù lójú gẹ́gẹ́ bí àṣẹ sí Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé Fún ìwọ ní èmi ó fún ní ilẹ̀ Kénánì gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún Nígbà tí wọn kéré níye, wọn kéré jọjọ, àti àwọn àjòjì níbẹ̀ Wọn ń lọ láti orílẹ̀ èdè sí orílẹ̀ èdè, láti ìjọba kan sí òmìrán Kò gba ẹnikẹ́ni láàyè láti pọ́n wọn lójú ó fi ọba bú nítorí tí wọn Má ṣe fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi, má sì ṣe wòlíì mi nibi Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà ó sì pa gbogbo ìpèṣè oúnjẹ wọn run Ó sì rán ọkùnrin kan ṣíwájú wọn Jósẹ́fù tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú Wọn fi sẹkẹ́sẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ Rẹ̀ a gbé ọrùn Rẹ̀ sínú irin Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọ tẹ́lẹ̀ fi ṣẹ títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre Ọba ránsẹ́ lọ tú u sílẹ̀ àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀ Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ Rẹ̀ aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní, Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ̀, kí ó máa ṣe àkóso àwọn ọmọ aládé kí ó sì kọ́ àwọn àgbà Rẹ̀ ní ọgbọ́n Ísírẹ́lì wá sí Éjíbítì Jákọ́bù sì ṣe àtìpó ní ilé Ámù Olúwa , sì mú àwọn ọmọ Rẹ̀ bí síi ó sì mú wọn lágbára jù àwọn ọ̀tá wọn lọ Ó yí wọn lọkàn padà láti korìíra àwọn ènìyàn láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ Ó rán Mósè ìránṣẹ́ Rẹ̀ àti Árónì tí ó ti yàn Wọn ń ṣé iṣẹ́ ìyanu láàrin wọn ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Ámù Ó rán òkùnkùn o sì mú ilẹ̀ ṣú wọn kò sì sọ̀rọ̀ òdì sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀, ó pa ẹja wọn Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá, èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣnṣin sì dìde, ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn Ó sọ òjò di yìnyín, àti ọ̀wọ́ iná ní ilẹ̀ wọn Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn ó sì dá igi orílẹ̀ èdè wọn Ó sọ̀rọ̀, eésú sì dé, àti kòkòrò ní àìníye, Wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn, wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn, ààyò gbogbo ipá wọ́n Ó mú Ísírẹ́lì jáde ti òun ti fàdákà àti wúrà, nínú ẹ̀yà Rẹ̀ kò sí aláìlera kan Inú Éjíbítì dùn nígbà tí wọn ń lọ, nítorí ẹ̀rù àwọn Ísírẹ́lí ń bá wọ́n Ó ta awọsánmọ̀ fún ìbòrí, àti iná láti fún wọn ni ìmọ́lẹ̀ lálẹ́ Wọn bèèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá, ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọ́n lọ́rùn Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde gẹ́gẹ́ bí odò tí ń ṣàn níbi gbígbẹ Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ Rẹ̀ àti Ábúráhámù ìránṣẹ́ Rẹ̀ Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn Rẹ̀ jáde pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ Rẹ̀ Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà, wọn sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà, Kí wọn kí ó le máa pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́ kí wọn kí ó le kíyèsí òfin Rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún Olúwa Sáàmù 106 Yin Olúwa Ẹ fi ìyìn fún Olúwa , nítorí tí o ṣeun Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun Nítorí tí ìfẹ́ Rẹ̀ dúró láéláé Ta ni ó le ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa ta ni lè sọ nípa ìyìn Rẹ̀ Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́ Ẹni tí tí ń ṣe ohun tí ó tọ́ Rántí mi, Olúwa , Nígbà tí ó bá fi ojú rere Rẹ̀ hàn, wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n, Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ìní Rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo Àwa ti dẹ́sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe àwa ti ṣe ohun tí kò dá a a sì ti hùwà búburú Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Éjíbítì iṣẹ́ ìyanu Rẹ kò yé wọn wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú Rẹ gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe sọ̀tẹ̀ sí ọ níbi òkun, àní nibi òkun pupa Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ Rẹ láti jẹ́ kí agbára ńlá Rẹ di mímọ̀ O bá òkun pupa wí, ó sì gbẹ o sì mú wọn la ìbú já bí ihà O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn láti ọwọ́ ọ̀tá ni ó ti gbà wọ́n Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn Nígbà náà wọn gba ìpínnú Rẹ gbọ́ wọ́n sì kọrin ìyìn Rẹ Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn Rẹ Nínú ihà ni wọn tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú aṣálẹ̀ wọn dán Ọlọ́run wò Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè fún ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mósè pẹ̀lú Árónì, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Dátanì mì ó bo ẹgbẹ́ Àbìrámù mọ́lẹ̀ Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yin Rẹ̀ iná jo àwọn ènìyàn búburú Ní Hórébù wọ́n ṣe ẹ̀gbọ̀rọ̀ màlúù wọn sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara ìrìn Wọn pa ògo wọn dà sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí í gbàwọ́n ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá fún Éjíbítì, Iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Ámù àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá òkun pupa Bẹ́ẹ̀ ní, ó sọ wí pé oun yóò pa wọ́n run bí kò ba ṣe tí Mósè, tí ó yàn, tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà tí ó pa ìbínú Rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́ Nígbà náà, wọn kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà wọn kò gba ilérí Rẹ̀ gbọ́ Wọn ń kùn nínú àgọ́ wọn wọn kò sì gbọ́ràn sí Olúwa Bẹ́ẹ̀ ni ó gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè sí wọn kí òun le jẹ́ kí wọn ṣubú nínú ihà, Láti jẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀ èdè láti fọ́nu wọn káàkiri lórí ilẹ̀ Wọn dá ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Péórù, wọn sì ń jẹ ẹbọ ti a rú sí àwọn òkú òrìṣà Wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe àjàkálẹ̀-àrùn jáde láàrin wọn Ṣùgbọ́n Fínéhásì dìde láti dá sí i, àjàkálẹ̀-àrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán A sì ka èyí sí òdodo fún un àti fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀ Níbi omi Méríbà, wọn bí Ọlọ́run nínú, ohun búburú wá sí orí Mósè nítorí wọn Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ẹ̀mí Ọlọ́run Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mósè wá Wọn kò pa àwọn ènìyàn run gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí sọ fún wọn, Ṣùgbọ́n wọn dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè, wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn tí o di ìkẹ́kùn fún wọn Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rúbọ àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìsà Wọn ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn Wọn fi wọ́n rúbọ sí ère Kénánì, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀ Wọn si fi ìṣe ara wọn sọ ara wọn di aláìmọ́, wọ́n sì ṣe panṣágà lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn Nígbà náà Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ó sì kórìíra àwọn ènìyàn Rẹ̀ Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀ èdè lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn sì jọba lórí wọn Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọ́n lójú wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n, Ṣíbẹ̀ wọ́n si ń ṣọ̀tẹ̀ sí ì wọ́n sì sòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn Ṣùgbọ́n o kíyèsí wọn nítorí ìṣòro nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn Ó rántí májẹ̀mú Rẹ̀ nítorí wọn Nítorí agbára ìfẹ́ Rẹ̀, ó ṣàánú wọn Lójú gbogbo àwọn tí o kó wọn ní ìgbèkùn ó mú wọn rí àánú Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa, kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrin àwọn aláìkọlà láti máa fí ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ Rẹ láti máa ṣògo nínú ìyìn Rẹ Olùbùkún ni Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì, láti ìrandíran Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, Àmín! Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ! Sáàmù 107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa , nítorí tí ó ṣeun nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ dúró láéláé Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí bayí, àwọn ẹni tí ó ràpadà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá, Àwọn tí ó kó jọ láti ilẹ̀ wọ̀nnì láti ìlà òòrùn àti ìwọ̀ òòrùn, láti àríwá àti òkun wá Wọn ń rìn káàkiri ni ihà ni ibi tí ọ̀nà kò sí, wọn kòrí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí wọn ó máa gbé Ebi ń pa wọn, òùngbẹ gbẹ wọn, ó sì Rẹ̀ ọkàn wọn nínú wọn Ní ìgbà náà wọn kígbe sókè sí Olúwa nínú ìdàámú wọn, ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú tí wọ́n lè máa gbé Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn, Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run ó sì fi ire fún ọkàn tí ebi ń pa Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, a dè wọ́n ni ìrora àti ní irin, Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọn kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá ògo, Ó sì fi ìkorò Rẹ àyà wọn sílẹ̀ wọn ṣubú, kò sì sí ẹni tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ Ní ìgbà náà wọ́n ké pe Olúwa nínú ìdàámú wọn, ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn Ó mú wọn jáde kúrò nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa Nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn Nítorí tí ó já ilẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì ó sì ke irin wọ̀n nì ní agbede-méjì Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ wọ́n sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ikú Nígbà náà wọn kígbe sí Olúwa nínú ìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdàámú wọn Ó rán ọ̀rọ̀ Rẹ̀, ara wọn sí dá ó sì yọ̀ wọ́n nínú isà òkú Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti iṣẹ ìyanu Rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́ kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ Rẹ̀ Àwọn ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí òkun nínú ọkọ̀ ojú omi, wọn jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá Wọn ri iṣẹ́ Olúwa , àti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ nínú ibú Nítorí tí ó pasẹ, ó sì mú ìjì fẹ́ tí ó gbé ríru Rẹ̀ sókè Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọn sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú nítorí ìpọ́njú ọkan wọn di omi Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn ọgbọ́n wọn sì dé òpin Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè sí Olúwa nínú ìdàámú wọn, ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn Ó sọ ìjì di ìdákẹ́-rọ́rọ́ bẹ́ẹ̀ ní rirú omi Rẹ̀ duro jẹ́ẹ́ Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀, ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ, Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárin àwọn ènìyàn kí wọn kí ó sì yín ín ní ìjọ àwọn àgbà Ó sọ odò di ihà, àti orisun omi di ilẹ̀ gbígbẹ Ilẹ̀ eleso di aṣálẹ̀ nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú Rẹ̀ O sọ ihà di adágún omi àti ilẹ̀ gbígbẹ di oríṣun omi Níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà, wọ́n sì pìlẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà tí yóò ma so èso tí ó dára Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dín kù Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú, ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù Ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ aládé ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira ó mú ìdílé wọn pọ̀ bi agbo ẹran Àwọn tí ó dúró sì ríi, inú wọn sì dùn ṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu Rẹ̀ mọ́ Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsí nǹkan wọ̀nyí kí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa Sáàmù 108 Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin èmi ó máa kọrin, èmi o máa fi ọkàn mi kọrin Jí ohun èlò orin àti háápù èmi ó jí ní kùtùkùtù Èmi ó yìn ọ, Ọlọ́run nínú àwọn orílẹ̀ èdè èmi o kọrin Rẹ nínú àwọn ènìyàn Nítorí tí o tóbi ní àánú Rẹ ju àwọn ọ̀run lọ àti òdodo Rẹ dé àwọ̀sánmọ̀ Gbé ara Rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run, àti ògo Rẹ lórí gbogbo ayé Gbà wá kí ó sì ràn wá lọ́wọ́, pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún Rẹ, se igbala, ki o si da mi lóhùn Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ níbi mímọ́ Ní ìsẹ́gun ní èmi ó ké Sékémù èmi yóò sì wọ́n ibi gíga Sukobù Gílíádì ni tèmi, Mánásè ni tèmi Éfuraimù ní ìbòrí mi Júdà ní olófin mi Móábù si ni ìkòkò ìwàsẹ̀ mi lórí Édómù ní èmi ó bọ́ bàtà mi sí lórí òkè Fílísitínì ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀ Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi Ta ni yóò sìn mi wá sí Édómù Ìwọ Ọlọ́run há kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀ Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́ Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni Nípaṣẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin nítorí oun ó tẹ àwọn ọ̀ta wa mọ́lẹ̀ Sáàmù 109 Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún Má ṣe dákẹ́ Nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn ti ya ẹnu wọn sí mi wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi Wọn fi ọ̀rọ̀ ìrira yí mi káàkiri wọ́n bá mi ja láìnídìí Nípo ifẹ̀ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi, ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà Wọ́n sì fi ibi san ire fún mi àti ìríra fún ìfẹ́ mi Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojú kọ ọ́ jẹ́ kí àwọn olufisùn dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ Kí a dá a lẹbi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́ kí àdúrà Rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀ Kí ọjọ́ Rẹ̀ kí ó kúrú kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ Rẹ̀ Kí àwọn ọmọ Rẹ̀ di aláìní baba kí aya Rẹ̀ sì di opó Jẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ máa ṣagbe kiri kí wọn máa tọrọ ounjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní jẹ́ kí àléjò kí o kó èrè isẹ́ Rẹ̀ lọ Má ṣe jẹ́ kí ẹnikan ṣe àánú fún un tàbí kí wọn káàánú lórí àwọn ọmọ Rẹ̀ aláìní baba Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ Rẹ̀ kúrò kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀ Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba Rẹ̀ kí ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ Olúwa Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwa kí o le ge ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀ Nítorí kò rántí láti ṣàánú, ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíní sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú, kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí Rẹ̀ bi inú Rẹ̀ kò ti dùn si ire, bẹ́ẹ̀ ni ki ó jìnnà sí ì Bí ó ti fi ègún wọ ará Rẹ̀ lásọ bí ẹ̀wù bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá si inú Rẹ̀ bí omi Jẹ́ kí o rí fún un bí aṣọ tí a dàbòó ní ara, àti fún àmùrè ti ó fi gbàjá nígbà gbogbo Èyí ni èrè àwọn ọ̀ta mi làti ọwọ́ Olúwa wá àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀kàn mi Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa , ṣe rere fún mi nítorí orúkọ Rẹ Nítorí ti àánú Rẹ dara, ìwọ gbà mí Nítorí pé talákà àti aláìní ni mí, àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi Èmi ń kọja lọ bí òjiji tí óńfà sẹ́yìn, mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú Eékún mi di aláìlera nítorí ààwẹ̀ gbígbà ẹran ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi nígbà tí wọn wò mí, wọn gbọn orí wọn Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ Rẹ ni èyí wí pé ìwọ, Olúwa , ni o ṣe é Wọ́n o máa gégùn-ún, ṣùgbọ́n ìwọ má súré Nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Rẹ yóò yọ̀ Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjú kí á sì fi ìdàrú dàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yìn Olúwa gidigidi ní àárin ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín Nítorí ó dúró ni apá ọ̀tún aláìní láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn Rẹ̀ lẹ́bi Sáàmù 11 Ìgbẹ́kẹ̀lé mí wà nínú Olúwa Báwo ní ẹ̀yin o ṣe sọ fún ọkàn mi pé Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè Rẹ Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà Rẹ̀ wọn ti ọfà wọn sí ojú okùn láti tafà níbi òjìjì sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin Nígbà tí ìpìlẹ̀ ba bàjẹ́ kí ni olódodo yóò ṣe Olúwa ń bẹ nínú tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ̀ Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ Rẹ̀ ní ọ̀run Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn ojú Rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò Olúwa ń yẹ olódodo wò, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ ìwà ipá ni ọkàn Rẹ̀ kórìíra Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò ẹ̀yín iná àti ìmí ọjọ́ tí ń jó àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn Nítorí olódodo ní Olúwa , o fẹ́ràn òdodo ẹni ìdúróṣinṣin yóò sì rí i Sáàmù 110 Olúwa sọ fún Olúwa mi, pé ìwọ jòkòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá Rẹ̀ di àpótí ìtisẹ̀ Rẹ Olúwa yóò na ọ̀pá agbára Rẹ̀ láti Síónì wá, ìwọ jọba láàrin àwọn ọ̀tá Rẹ Àwọn ènìyàn Rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá ní ọjọ́ ìjáde ogun Rẹ, nínú ẹwà mímọ́, láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà Rẹ Olúwa ti búra, kò sí ní yí ọkàn padà pé, ìwọ ní àlúfà títí láé, titẹ̀ àpẹẹrẹ Melekisédékì Olúwa ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ni yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú Rẹ̀ Yóò ṣe ìdájọ́ láàrin kènfèrí, yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò Yóò mú nínú òdò ṣíṣàn ní ọ̀nà nítorí náà ni yóò ṣe gbe orí sókè Sáàmù 111 Ẹ máa yin Olúwa Èmi yóò máa yìn Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, ní àwujọ àwọn olóòtọ́, àti ní ijọ ènìyàn Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú Rẹ̀ Iṣẹ́ Rẹ̀ ní ọlá ńlá àti ògo àti òdodo Rẹ̀ dúró láéláé Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, láti máa rántí Olúwa ni olóore ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú O ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ oun ń rántí májẹ̀mú Rẹ̀ Ó ti fi hàn àwọn ènìyàn Rẹ̀ agbára isẹ́ Rẹ̀ láti fún wọn ní ilẹ̀lérí ni ìní Iṣẹ́ ọwọ Rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́ gbogbo òfin Rẹ̀ sì dájú Wọ́n dúró láé àti láé, ní òtítọ́ àti òdodo ní a ṣe wọ́n Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ó pàṣẹ májẹ̀mú Rẹ̀ títí láé mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ní orúkọ Rẹ̀ Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin Rẹ̀ ìyìn Rẹ̀ dúró láé Sáàmù 112 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ìbùkún ni fún Ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó ní inúdídùn ńlá sí àwọn òfin Rẹ̀ Iru ọmọ Rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé ìran àwọn olóòótọ́ ni a ó bùkún fún Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé Rẹ̀ òdodo Rẹ̀ sì dúró láé Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ni òkùnkùn olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo Ọkùnrin rere fí ojú rere hàn, a sì wín ni, ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ Rẹ̀ Dájúdájú kì yóò le yí ni ìpo padà láéláé olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí ní ayérayé Òun kì yóò bèèrè ìyìn búburú ọkàn Rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa Ó ti mú ọkàn Rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bàá, títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkan Rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá Rẹ̀ Ó ti pin ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú Nítorí òdodo Rẹ̀ dúró láé ìwọ Rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá Ènìyàn búburú yóò rí, inú wọn yóò sì bàjẹ́, yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù èròngbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé Sáàmù 113 Ẹ máa yin Olúwa , yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa , ẹ yin orúkọ Olúwa Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé Láti ìlà òòrun títí dé ìwọ Rẹ̀ orúkọ Olúwa ni kí á máa yìn Olúwa ga lórí gbogbo ayé, àti ògo Rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa, tí ó gbé ní ibi gíga Tí ó Rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀ láti wò òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé! Ó gbé òtòsì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá Kí ó le mú-un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ aládé àní pẹ̀lú àwọn ọmọ aládé àwọn ènìyàn Rẹ̀ Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé, àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ Rẹ̀ Ẹ yin Olúwa Sáàmù 114 Nígbà tí Ísírẹ́lì jáde ní Éjíbítì, ilé Jákọ́bù láti inú ènìyàn àjòjì èdè Júdà wà ní ibi mímọ́, Ísírẹ́lì wà ní ìjọba Òkun sì rí i, ó sì wárìrì Jódáni sì padà sẹ́yìn Àwọn òkè ńlá ń fò bí agbo àti òkè kékèké bí ọ̀dọ́ àgùntàn Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ òkun, tí ìwọ fi wárìrì Ìwọ Jódánì, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí agbo, àti ẹ̀yin òkè kékèké bí ọ̀dọ́ àgùntàn Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa ní iwájú Ọlọ́run Jákọ́bù tí ó sọ àpáta di adágún omi, àti òkúta-ìbọn di orísun omi Sáàmù 115 Kí ṣe fún wa, Olúwa kì ṣe fún wá, ṣùgbọ́n fún orúkọ Rẹ̀ ní a fi ògo fún, fún àánú àti òtítọ́ Rẹ Torí kí ní àwọn aláìkọlà yóò ṣe sọ pé, níbo ni Ọlọ́run wa wà Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú Òrìṣà fàdákà àti wúrà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn Wọn ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ̀rọ̀, wọn ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ràn wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọ́n kò fi gbóòórùn Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó, wọ́n ní ẹṣẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn gẹ́gẹ́ bẹ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ Rẹ̀ lé wọn Ìwọ Ísírẹ́lì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn Ẹ yin ilé Árónì, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa oun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa , gbẹ́kẹ̀lé Olúwa oun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa yóò bùkún ilé Ísírẹ́lì yóò bùkún ilé Árónì Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa , àti kékeré àti ńlá Olúwa yóò mú ọ pọ̀ síi síwájú àti síwájú, ìwọ àti àwọn ọmọ Rẹ̀ Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé Ọ̀run àní ọ̀run ni ti, Olúwa ṣùgbọ́n ayé lo fi fún ọmọ ènìyàn Òkú kò le yìn Olúwa , tàbí ẹni tí o ti lọ sí ìṣàlẹ̀ ìdákẹ́jẹ́ Ṣùgbọ́n àwa o fi ìbùkún fún Olúwa láti ìsinsìn yí lọ àti títí láéláé Ẹ yin Olúwa Sáàmù 116 Èmi fẹ́ràn Olúwa , nítorí ó gbọ́ ohùn mi ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú Nítorí ó yí etí Rẹ̀ padà sí mi, èmi yóò máa, pè é ní wọ̀n ìgbà tí mo wà láàyé Òkun ikú yí mi ka, ìrora isà òkú wá sórí mi ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi Nígbà náà ni mo ké pé orúkọ Olúwa Olúwa , èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́ ó sì ní òdodo Ọlọ́run wa kún fún àánú Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́ nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi Rẹ, nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ Nítorí ìwọ, Olúwa , ti gba ọkàn mi kúrò lọ́wọ́ ikú, ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé, àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú, Nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwa ní ilẹ̀ alààyè Èmi gbàgbọ́ nítorí náà mo wí pé, èmi rí ìpọ́njú púpọ̀ Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé Èké ni gbogbo ènìyàn Kí ni èmi yóò san fún Olúwa nítorí gbogbo rere Rẹ̀ sí mí Èmi yóò gbé aago ìgbàlà sókè èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa ní ojú àwọn ènìyàn Rẹ̀ Iyebíye ní ojú Olúwa àti ikú àwọn ẹni mímọ́ Rẹ̀ Olúwa , ní tòótọ́ ìránṣẹ́ Rẹ ni mo jẹ́ èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ, ọmọ ìránṣẹ́-bìnrin Rẹ ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ èmi yóò sì képe orúkọ Olúwa Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn Rẹ̀, Nínú àgbàlá ilé Olúwa ni àárin Rẹ̀, ìwọ Jérúsálẹ́mù Ẹ yin Olúwa Sáàmù 117 Ẹ yin Olúwa , gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀ èdè ẹ pòkìkí Rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Nítorí ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ tí ó ní sí wa, àti òtítọ́ Olúwa dúró láéláé Ẹ yin Olúwa ! Sáàmù 118 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa , nítorí tí ó dára àánú Rẹ̀ dúró láéláé Jẹ́ kí Ísírẹ́lì wí pé Àánú Rẹ̀ dúró láéláé Jẹ́ kí ilé Árónì wí pé Àánú Rẹ̀ dúró láéláé Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé Àánú Rẹ̀ dúró láéláé Nínú ìrora mi, mo sunkún sí Olúwa , ó sì dámi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀ Olúwa , ń bẹ fún èmi èmi kì yóò bẹ̀rù Kí ni ènìyàn lè ṣe si mi Olúwa n bẹ fún mi òun ni olùrànlọ́wọ́ mi Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìfẹ́ mi lórí àwọn ti ó kórìíra mi Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ aládé lọ Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè yí mi káàkiri, ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn kúrò Wọn yí mi ká kiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́, ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn dànù Wọn gbá yìnìn yí mí ká bí oyin, ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún ní orúkọ Olúwa èmi ké wọn dànù Ìwọ tì mi gidigidi kí ń lè subú, ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́ Olúwa ni agbára àti orin mi ó si di ìgbàlà mi Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára! Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbé ga ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára! Èmi kì yóò kú ṣùgbọ́n èmi yóò yè, èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe Olúwa bá mi wí gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́ Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà òdodo fún mi èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwa ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dámi lóhùn ìwọ sì di ìgbàlà mi Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀ ni ó di pàtàkì òkúta igun ilé Olúwa ti ṣe èyí ó ṣe ìyanu ní ojú wa Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú Rẹ̀ Olúwa , gbà wá Olúwa , fún wa ní àlàáfíà Ìbùkún ni fún àwọn tí ó wá ní orúkọ Olúwa Láti ilé Olúwa wá ní àwa fi ìbùkún fún ọ Olúwa ni Ọlọ́run, ó ti mú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn sí wa lára pẹ̀lú ẹká igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀ ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa , nítorí tí ó ṣeun nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Sáàmù 119 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́sẹ̀, ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa , Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin Rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn Wọn kò ṣe ohun tí kò dára wọ́n rìn ní ọ̀nà Rẹ̀ Ìwọ ti la ìlànà Rẹ̀ sílẹ̀ kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin láti máa pa òfin Rẹ̀ mọ́! Nígbà náà, ojú kò ní tì mí nígbà tí mo bá ń kíyèsí àṣẹ Rẹ̀ gbogbo Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo Rẹ̀ Èmi yóò gbọ́ràn sí asẹ Rẹ̀ Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátapáta Báwo ni àwọn èwe ènìyàn yóò ti ṣe pa ọ̀nà Rẹ̀ mọ́ Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ Rẹ Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi má ṣe jẹ́ kí èmi yàpa kúrò nínú àṣẹ̀ Rẹ Èmi ti pa ọ̀rọ̀ Rẹ mọ́ ní ọkàn mi kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ Ìyìn ni fún Olúwa kọ́ mi ní àsẹ Rẹ Pẹ̀lú ètè mi èmi tún sírò gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu Rẹ Èmi yọ̀ nínú títẹ̀lé òrin Rẹ bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọlá ńlá Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà Rẹ èmi sì kíyèsí ọ̀nà Rẹ Inú mi dùn sí àṣẹ Rẹ èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà Rẹ Ṣe rere sí ìránṣẹ́ Rẹ, èmi yóò sì wà láàyè èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ La ojú mi kí èmi lè ríran rí ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin Rẹ Àlejò ní èmi jẹ́ láyé Má ṣe pa àṣẹ Rẹ mọ́ fún mi Ọkàn mi pòrúúru pẹ̀lú ìfojúsọ́nà nítorí òfin Rẹ nígbà gbogbo Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn-ún tí ó sìnà kúrò nínú àṣẹ Rẹ Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi, nítorí èmi pa òfin Rẹ mọ́ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọ̀pọ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Rẹ̀ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ Rẹ Òfin Rẹ ni dídùn inú mi àwọn ní olùbadámọ̀ràn mi Èmi tẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ sínú erùpẹ̀ pa ayé mi mọ́ sí ipa ọ̀rọ̀ Rẹ Èmi tún ọ̀nà mi síròṣ ìwọ sì dá mí lóhùn kọ́ mi ní àṣẹ Rẹ Jẹ́ kí ń mọ ẹ̀kọ́ ìlànà Rẹ̀ nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu Rẹ Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́ fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn fún mi ní oore ọ̀fẹ́ nípa òfin Rẹ Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́ èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin Rẹ Èmi yára di òfin Rẹ mú Olúwa má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ Rẹ, nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀ kọ́ mi, Olúwa , láti tẹ̀lé àṣẹ Rẹ nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́ èmi yóò sì máa kíyèsíi pẹ̀lú ọkàn mi Fi ipa ọ̀nà àṣẹ Rẹ hàn mí, nítorí nínú Rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn Yí ọkàn mi padà sí òfin Rẹ̀ kí ó má ṣe sí ojú kòkòrò mọ́ Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán pa ayé mí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ Mú ìlérí Rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ Rẹ, nítorí òfin Rẹ dára Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù ni torí tí idájọ́ Rẹ dára Kíyèsíi ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ Rẹ! Pa ayé mí mọ́ nínú òdodo Rẹ Jẹ́ kí ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa , ìgbàlà Rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ Nígbà náà ni èmi yóò dá ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn, nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ Rẹ Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ Rẹ Èmi yóò máa gbọ́ràn sí òfin Rẹ nígbà gbogbo láé àti láéláé Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira, nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ Rẹ̀ jáde Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin Rẹ níwájú àwọn ọba ojú kì yóò sì tì mí, Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ Rẹ nítórí èmi ni ìfẹ́ wọn Èmi gbé ọwọ̀ mi sókè nítorí àṣẹ Rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn, èmi sì ń ṣe àsàrò òfin Rẹ̀ Rántí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sí ìránṣẹ́ Rẹ, nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí ìpinu Rẹ pa ayé mi mọ́ Àwọn agbéraga fi mi ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró, ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin Rẹ Èmi rántí àwọn òfin Rẹ ìgbàanì, Olúwa , èmi sì rí ìtùnú nínú wọn Ìbínú dìmí mú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú tí wọ́n ti kọ òfin Rẹ sílẹ̀ Òfin Rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi níbikíbi tí èmi ń gbé Ní òru èmi rántí orúkọ Rẹ, Olúwa , èmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́ nitori ti mo gba ẹ̀kọ́ Rẹ gbọ́ Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ Rẹ Èmi ti wá ojú Rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi fún mi ní oore ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ Èmi ti kíyèsí ọ̀nà mi èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin Rẹ Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra láti gbọ́ràn sí àṣẹ Rẹ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn, èmi kò ní gbàgbé òfin Rẹ Ní àárin ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ nítorí òfin òdodo Rẹ̀ Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ, sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ Rẹ̀ Ayé kún fún ìfẹ́ Rẹ Olúwa Kọ́ mi ní òfin Rẹ Ṣe rere sí ìránṣẹ́ Rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ, Olúwa Kọ́ mi ni ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere, nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ Rẹ Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti sìnà, ṣùgbọ́n ni ìsinsinyí èmi gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni kọ́ mi ní ìlànà Rẹ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti Rẹ̀ mí pẹ̀lú èké èmi pa ẹ̀kọ́ Rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú, ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin Rẹ Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin Rẹ Òfin tí ó jáde láti ẹnu Rẹ ju iyebíye sí mi lọ ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ Ọwọ́ Rẹ ní ó dá mi tí ó sì mọ mí fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ Rẹ Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi, nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ Èmi mọ̀, Olúwa , nítorí òfin Rẹ òdodo ni, àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú Kí ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi, gẹ́gẹ́ bí ìpinu Rẹ sí ìránṣẹ́ Rẹ Jẹ́ kí àánú Rẹ kí ó tọ̀ò mí wá kí èmi kí ó lè yè, nítorí òfin Rẹ̀ jẹ́ ìdùnnú mi Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga nítorí wọn pamí lára láìnídìí ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ Rẹ̀ Kí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ yí padà sí mí, àwọn tí ó ní òye òfin Rẹ Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin Rẹ, kí ojú kí ó má ṣe tì mí Ọkàn mi ń fojú sọ́nà nítorí ìgbàlà Rẹ, ṣùgbọ́n èmi tí mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wí wo ìpinu Rẹ èmi wí pé, Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí àmọ́ wáìnì nínú èéfín, èmi kò gbàgbé òfin Rẹ Báwo ni ìránṣẹ́ Rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi, tí ó lòdì sí òfin Rẹ Gbogbo àsẹ Rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé rànmílọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láì nídìí Wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé, ṣùgbọ́n èmi kò kọ̀ ẹ̀kọ́ Rẹ Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ, èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu Rẹ̀ gbọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ, Olúwa , títí láé ni ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run Òtítọ́ Rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin Òfin Rẹ dúró di òní nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́ Bí òfin Rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi, èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ Rẹ láé, nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́ Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ èmi ti wá ẹ̀kọ́ Rẹ Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run, ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsí ẹ̀rí Rẹ Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin ṣùgbọ́n àṣẹ Rẹ aláìlópin ni Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin Rẹ tó! Èmi ń ṣe àṣàrò nínú Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá Àṣẹ Rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀ta mi lọ, nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé Èmi ní iyè ińu ju gbogbo olùkọ́ mi lọ, nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin Rẹ Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ, nítorí mo gba ẹ̀kọ́ Rẹ Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ Rẹ Èmi kò yà kúrò nínú òfin Rẹ, nítorí ìwọ fún rarẹ̀ ni ó kọ́ mi Báwo ni ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó, ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi! Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ Rẹ nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ ni ó ṣe fítílà sí ẹṣẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo Rẹ A pọ́n mi lójú gidigidi Olúwa , sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Rẹ Olúwa , gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi, kí o sì kọ́ mi ní òfin Rẹ̀ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo, èmi kò ní gbàgbé òfin Rẹ Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n èmi kò sìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ Rẹ Òfin Rẹ ni ogún mi láéláé àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi Ọkàn mi ti lé pípa òfin Rẹ mọ́ láé dé òpin Èmi kóríra àwọn ọlọ́kàn méjì, ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin Rẹ Ìwọ ni ààbò mi àti aṣà mi èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú, kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́! Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ, kí èmi kí ó lè yè Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin Rẹ Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó sìnà kúrò nínú òfin Rẹ, nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́ nítorí náà, èmi fẹ́ òfin ẹ̀ Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí Rẹ̀ èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin Rẹ Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́ má ṣe fi mi sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ Rẹ dájú má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára Ojú mi kùnà, fún wí wo ìgbàlà Rẹ, fún wíwo ìpinu òdodo Rẹ Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ Rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ Rẹ kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ Rẹ Èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ ẹ fún mi ní òye kí èmi lè ní òye òfin Rẹ Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa nítorí òfin Rẹ ti fọ́ Nítorí èmi fẹ́ràn àsẹ Rẹ ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ, Nítorí èmi kíyèsí gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ Rẹ̀, èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú Òfin Rẹ̀ ìyanu ni nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́ Ìṣípayá ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá ó fi òye fún àwọn òpè Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ, nítorí èmi fojú sọ́nà sí ṣsẹ Rẹ Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi, bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ Rẹ Fi ìsísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Rẹ, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn, kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ Rẹ Jẹ́ kí ojú Rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ Rẹ lára kí ó sì kọ́ mi ní àsẹ Rẹ Omijé sàn jáde ní ojú mi, nítorí wọn kò gba òfin Rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ Olódodo ni ìwọ Olúwa ìdájọ́ rẹ sì dúró sinsin Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé Ìtara mi ti pami run, nítorí àwọn ọ̀ta mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ Rẹ dá Wọ́n ti dán ìpinnu Rẹ wò pátapáta ìránṣẹ́ Rẹ sì fẹ́ràn wọ́n Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ Rẹ Òdodo Rẹ wà títí láé òtítọ́ ni òfin Rẹ̀ Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi, ṣùgbọ́n àsẹ Rẹ ni inú dídùn mi, Òfin Rẹ jẹ́ òtítọ́ láé fún mi ní òyé kí èmi lè yè èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi dámi lóhùn Olúwa , èmi yóò sì gbọ́ràn sí àsẹ Rẹ Èmi kígbe pè ọ́ gbà mí èmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́ Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìràn lọ́wọ́ èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ Ojú mi ṣááju ìsọ́ òru, nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ r Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ pa ayé mí mọ́, Olúwa , gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòòsí, ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin Rẹ Ṣíbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa , àti gbogbo àsẹ Rẹ jẹ́ òtítọ́ Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin Rẹ tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí, nítorí èmi kò gbàgbé òfin Rẹ Gba ẹjọ́ mi rò kí ó sì rà mí padà pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú nítorí wọn kò wá àṣẹ Rẹ Ìyọ́nú Rẹ̀ tóbi, Olúwa pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀ta tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi, ṣùgbọ́n èmi kò tíì yí padà kúrò nínú òfin Rẹ Èmi wọ̀ àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́ nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ Rẹ gbọ́ Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ Rẹ pa ayé mi mọ́, Olúwa , gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ Rẹ gbogbo òfin òdodo Rẹ láéláé ni Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí, ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ Rẹ Èmi yọ̀ nínú ìpinnu Rẹ bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀ Èmi kórìíra mo sì gba èké ṣíṣe ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin Rẹ Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́ nítorí òfin òdodo Rẹ Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin Rẹ, kò sì si ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀ Èmi yóò dúró de ìgbàlà Rẹ, Olúwa , èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ Rẹ Èmi gba òfin Rẹ gbọ́, nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀ púpọ̀ Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ Rẹ àti òfin Rẹ, nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú Rẹ, Olúwa fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú Rẹ gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ Ètè mi yóò sọ ìyin jáde, nítorí ìwọ kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ Rẹ, nítorí gbogbo àṣẹ Rẹ jẹ́ òdodo Jẹ́ kí ọwọ́ Rẹ ṣetan láti rànmílọ́wọ́, nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ Rẹ Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà Rẹ, Olúwa , àti òfin Rẹ jẹ́ dídùn inú mi Jẹ́ kí èmi wà láàyè ki èmi lè yìn ọ́, kí o sì jẹ́ kí òfin Rẹ mú mi dúró Èmí ti sìnà bí àgùntàn tí ó sọnùú wá ìránṣẹ́ Rẹ, nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ Rẹ Sáàmù 12 Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa nítorí ẹni ìwà bí Ọlọ́run kò sí mọ́ Olótìítọ́ tí pòórá kúrò láàrin àwọn ènìyàn Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀ ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn Kí Olúwa kí ó gé ètè èké wọn àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu tí ó wí pé, Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa àwa ní ètè wa ta ni ọ̀gá wa Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkéróra àwọn aláìní, Èmi yóò dìde nísinsin yìí ni Olúwa wí Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù, gẹ́gẹ́ bí fàdákà ti a yọ́ nínú ìléru àmọ́, tí a sọ di mímọ́ nígbà méje Olúwa , ìwọ yóò pa wá mọ́ kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kiri nígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òṣì láàrin àwọn ènìyàn Sáàmù 120 Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi, ó sì dámi lóhùn Gbà mí, Olúwa , kúrò lọ́wọ́ ète èké àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn Kí ni kí a fi fún ọ Àti kín kí a tún ṣe fún ọ, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn Òun yóò bá ọ́ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun, pẹ̀lú eyin iná igi ìgbálẹ̀ Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Mésékì, nítorí èmi gbé nínú àgọ́ Kédárì! Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé láàrin àwọn tí ó kóríra àlàáfíà Ènìyàn àlàáfíà ni mí ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni ti wọn Sáàmù 121 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì— níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé Òun kì yóò jẹ́ kí ẹṣẹ̀ Rẹ̀ kí ó yẹ̀ ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé Kíyèsí, ẹni tí ń pa Ísírẹ́lì mọ́, kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn Olúwa ni olùpamọ́ Rẹ Olúwa ní òjìji Rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ Oòrùn kì yóò pa ọ ní ìgbà ọ̀sán tàbí òṣùpá ní ìgbà òru Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo yóò pa ọkàn Rẹ mọ́ Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ Rẹ mọ́ láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé Sáàmù 122 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé Ẹ jẹ́ kí a lọ sílé Olúwa Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè Rẹ, ìwọ Jérúsálẹ́mù Jérúsálẹ́mù, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ, àwọn ẹ̀yà Olúwa , ẹ̀rí fún Ísírẹ́lì, láti máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀, àwọn ìtẹ́ ilé Dáfídì Gbàdúrà fún àlàáfíà Jérúsálẹ́mù àwọn tí o fẹ́ ọ yóò ṣe rere Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi Rẹ̀, àti ire nínú ààfin Rẹ̀ Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi èmi yóò wí nísinsìyí pé, kí àlàáfíà kí ó wà nínú Rẹ̀ Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa, èmi yóò máa wá ire Rẹ̀ Sáàmù 123 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí, ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run Kíyèsí, bí ojú àwọn ìránṣẹ́ kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn, àti bí ojú ìránṣẹ́-bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá Rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa, títí yóò fi ṣàánú fún wa Olúwa , ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀ púpọ̀ Ọkàn wa kún púpọ̀ fún ẹ̀gàn àwọn onírera, àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga Sáàmù 124 Ìba má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa ni kí Ísírẹ́lì kí ó máa wí nísinsìn yìí Ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa, Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láàyè nígbà tí ìbínú wọn ru sí wá Nígbà náà ni omi wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀ Nígbà náà ni agbéraga omi ìbá borí ọkàn wa Olùbùkún ni Olúwa , tí kò fi wá fún wọ́n bí ohun ọdẹ fún eyín wọn Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ okùn já àwa sì yọ Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa , tí ó dá ọ̀run òun ayé Sáàmù 125 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Síónì, tí a kò lè sí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé Bí òkè ńlá ti yí Jérúsálẹ́mù ká, bẹ́ẹ̀ ní Olúwa yí ènìyàn ká láti ìsinsìnyí lọ àti títí láéláé Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo kí àwọn olódodo kí o máa ba fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀ Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere, àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Ísírẹ́lì Sáàmù 126 Nígbà tí Olúwa mú ìkòlọ Síónì padà, àwa dàbí ẹni tí o ń lá àlá Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín, àti ahọ́n wa kọ orin nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn aláìkọlà pé, Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa nítorí náà àwa ń yọ̀ Olúwa mú ìkólọ wa padà, bí ìṣàn omi ní gúsù Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòtọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí Rẹ̀ Sáàmù 127 Bí kò ṣè pé Olúwa bá kọ́ ile náà àwọn tí n kọ ọ ńṣiṣẹ́ lásán ni bí kò sé pé Olúwa bá pa ilú mọ́, olùṣọ́ jí lásán Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù lati pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ́ làálàá bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ire fún olùfẹ́ Rẹ̀ lójú ọ̀run Kíyèsí i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa ọmọ inú sì ni èrè Rẹ̀ Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ààbò Rẹ̀ kún fún wọn ojú kì yóò tì wọ́n, ṣùgbọ́n wọn yóò sẹ́gun àwọn ọ̀ta ní ẹnu ọ̀nà Sáàmù 128 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà Rẹ̀ Nítorí tí ìwọ yóò jẹ isẹ́ ọwọ́ Rẹ ìbùkún ni fún ọ yóò sì dára fún ọ Obìnrin Rẹ yóò dà bí àjàrà rere eléso púpọ̀ ní àárin ilé Rẹ àwọn ọmọ Rẹ yóò dà bí igi olífì tí ó yí tábìlì Rẹ ká Kíyèsíi pé, bẹ́ẹ̀ ni a o bù síi fún ọkùnrin náà, tí o bẹ̀rù Olúwa Kí Olúwa kí o bù síi fún ọ láti Síónì wá, kí ìwọ kí ó sì máa rí ire Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ ayé Rẹ gbogbo Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí o sì máa rí àti ọmọ dé ọmọ Rẹ àti àlàáfíà lára Ísírẹ́lì Sáàmù 129 Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá ni kí Ísírẹ́lì kí ó wí nísinsinyí Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá ṣíbẹ̀ wọn kò tíì borí mi Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi wọ́n sì là aporo wọn gígùn Olódodo ní Olúwa ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò Kí gbogbo àwọn tí ó korìíra Síónì kí ó dààmú, kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀ tí ó gbẹ dànù kí o tó dàgbà sókè Èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ Rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ẹni tí ń di ìtì, kó kún apá Rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kó wí pé, ìbùkún Olúwa kí o pẹ̀lú yín àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa Sáàmù 13 Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú Rẹ pamọ́ fún mi Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà, àti ní ojojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi Yóò ti pẹ́tó tí àwọn ọ̀ta mi yóò máa borí mi Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sùn oorun ikú Ọ̀tá mi wí pé, Èmi ti ṣẹ́gun Rẹ̀, àwọn ọ̀ta mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà Rẹ Èmi ó kọrin sí Olúwa , nítorí ó dára sí mi Sáàmù 130 Láti inú ibú wá ní èmi ń képè ọ Olúwa Olúwa , gbóhùn mi, jẹ́ kí etí Rẹ̀ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi Olúwa , ìbáṣe pé kí ìwọ kí o máa ṣàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa , tà ni ìbá dúró Nítorí ìdàríjìn wà lọ́dọ̀ Rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù Rẹ Èmi dúró de Olúwa , ọkàn mi dúró, àti nínú ọ̀rọ̀ Rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí Ọkàn mi dúró de Olúwa , ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ, àní ju àwọn ti ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ Ísírẹ́lì, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà, àti lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáńdè wà Òun ó sì dá Ísírẹ́lì ní ìdè kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ gbogbo Sáàmù 131 Olúwa àyà mí kò gbéga bẹ́ẹ̀ ní ojú mi kò gbé sókè bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá, tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi, mo sì mú-un dákẹ́jẹ́ẹ́, bí ọmọ tí a fi ọwọ ìyá Rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú ọkàn mí rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú Ísírẹ́lì, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa láti ìsinsinyí lọ àti láéláé Sáàmù 132 Olúwa , rántí Dáfídì nínú gbogbo ìpọ́njú Rẹ̀ Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa , tí ó sì ṣe ìlèrí fún Alágbára Jákọ́bù pé Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ, bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gùn orí àkéte mi Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi, tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi, Títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa , ibùjókòó fún Alágbára Jákọ́bù Kíyèsí i, àwa gbúroo Rẹ̀ ni Éfúrátà àwa rí i nínú oko ẹgàn náà Àwa ó lọ sínú àgọ́ Rẹ̀ àwa ó máa sìn níbi àpótí-ìtìsẹ̀ Rẹ̀ Olúwa , dìde sí ibi ìsinmi Rẹ ìwọ, àti àpótí agbára Rẹ Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà Rẹ kí àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀ Nítorí tí Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀ Má ṣe yí ojú ẹni-òróró Rẹ padà Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dáfídì Òun kí yóò yípadà kúrò nínú Rẹ̀, nínú irú ọmọ inú Rẹ ní èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ Rẹ Bí àwọn ọmọ Rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́ àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn, àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókoo lórí ìtẹ́ Rẹ láéláé Nítorí tí Olúwa ti yan Síónì ó ti fẹ́ẹ fún ibùjókòó Rẹ̀ Èyí ní ibi ìsinmi mí láéláé níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé nítorí tí mo fẹ́ ẹ Èmi yóò bùkún oúnjẹ Rẹ̀ púpọ̀ púpọ̀ èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà Rẹ̀ lọ́rùn Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlúfáà Rẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀ Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwọ Dáfídì yọ̀, èmi ti ṣe ìlànà fítílà kan fún ẹni òróró mi Àwọn ọ̀tá Rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀ ṣùgbọ́n lára Òun tìkararẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀ Sáàmù 133 Kíyèsí, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀ Ó dàbí òróró ìkúnra iyebíye ní orí, tí ó ṣàn dé irungbọ̀n, àní irungbọ̀n Árónì tí ó sì ṣàn sí etí aṣọ sórí Rẹ̀ Bí irì Hémónì tí o ṣàn sórí òke Síónì nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún, àni ìyè láéláé Sáàmù 134 Ẹ kíyèsí i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa , gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa , tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́, kí ẹsì fi ìbùkún fún Olúwa Olúwa tí ó dá ọ̀run Òun ayé, kí ó bùsí i fún ọ láti Síónì wá Sáàmù 135 Ẹ yìn Olúwa , ẹ yìn orúkọ Olúwa Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa , nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa Ẹ yin Olúwa nítorí tí Olúwa ṣeun ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ̀ ní torí tí ó dùn Nítorí tí Olúwa ti yàn Jákọ́bù fún ara Rẹ̀ àní Ísírẹ́lì fún ìṣúra ààyò Rẹ̀ Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi, àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ Ohunkóhun tí ó wu Olúwa , Òun ní iṣe ní ọ̀run, àti ní ayé, ní òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo Ó mú ìkuku góke láti òpin ilẹ̀ wá ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjo ó ń mú afẹ́fé ti inú ilẹ̀ ìṣúra Rẹ̀ wá Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Éjíbítì, àti tí ènìyàn àti ti ẹranko Ẹni tí ó rán àmì àti iṣẹ ìyanu sí àrin Rẹ̀, ìwọ Éjíbítì, sí ara Fáráò, àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ gbogbo Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀, tí ó sì pa àwọn alágbára ọba Síónì, ọba àwọn ará Ámorì, àti Ógù, ọba Báṣánì, àti gbogbo ìjọba Kénánì Ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni ní ìní, ìní fún Ísírẹ́lì, ènìyàn Rẹ̀ Olúwa orúkọ Rẹ dúró láéláé ìrántí Rẹ Olúwa , láti ìran-díran Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀, yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ̀ Sílífà Òun wúrà ní èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn Wọn ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọ́n kò sọ̀rọ wọn ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́ràn bẹ́ẹ̀ ni kò si èèmí kan ní ẹnu wọn Àwọn tí ó ṣe wọn dàbí wọn bẹ́ẹ̀ sì ní olúkùlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé wọn Ẹ̀yin ara ilé Ísírẹ́lì, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa , ẹ̀yin ará ilé Árónì, fi ìbùkún fún Olúwa Ẹ̀yin ará ilé Léfì, fi ìbùkún fún Olúwa ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa , fi ìbùkún fún Olúwa Olùbùkún ní Olúwa , láti Síónì wá, tí ń gbé Jérúsálẹ́mù Ẹ fi ìyìn fún Olúwa Sáàmù 136 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn Olúwa , nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Òòrùn láti jọba ọ̀sán nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Òsùpá àti ìràwọ̀ láti jọba òru nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Fún ẹni tí ó kọlu Éjíbítì lára àwọn àkọ́bí wọn nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Ó sì mú Ísírẹ́lì jáde kúrò láàrin wọn nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Fún ẹni tí ó pín òkun pupa ní ìyà nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Ó sì mú Ísírẹ́lì kọjá láàrin Rẹ̀ nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Ṣùgbọ́n ó bi Fáráò àti ogun Rẹ̀ ṣubú nínú òkun pupa nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn Rẹ̀ la ihà já nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Fún ẹni tí ó kọ lu àwọn ọba ńlá nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Ó sì pa àwọn ọba olókìkí nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Síónì, ọba àwọn ará Ámórì nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Àti Ógù, ọba Báṣánì nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni ní ìní, nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Ìní fún Ísírẹ́lì, ìránṣẹ́ Rẹ̀, nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé Sáàmù 137 Ní ẹ̀bá odò Bábílónì, níbẹ̀ ní àwa gbé jókòó àwa sì sunkún nígbà tí àwa rántí Síónì Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílóò, tí ó wà láàrin Rẹ̀ Nítorí pé níbẹ̀ ní àwọn tí ó kó wa ní ìgbékùn bèèrè orin lọ́wọ́ wá, àti àwọn tí ó ni wá lára bèèrè ìdárayá wí pé ẹ kọ orin Síónì kan fún wa Àwa o ti ṣe kọ orin Olúwa ni ilẹ̀ àjèjì Jérúsálẹ́mù, bí èmi bá gbàgbé Rẹ jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò Rẹ Bí èmi kò bá rántí Rẹ, jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi bí èmi kò bá fi Jérúsálẹ́mù ṣáájú olórí ayọ̀ mi gbogbo Olúwa rántí ọjọ́ Jérúsálẹ́mù, lára àwọn ọmọ Édómù, àwọn ẹni tí ń wí pé, wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ de ìpílẹ̀ Rẹ̀! Ìwọ, ọmọbìnrin Bábílónì, ẹni tí a o parun ìbùkún ní fún ẹni tí ó san án fún ọ bí ìwọ ti rò sí wa Ìbùkún ní fún ẹni tí ó mú tí ó sì fi ọmọ wẹ́wẹ́ Rẹ̀ ṣán òkúta Sáàmù 138 Èmi yóò yìn ọ́ tinú tinú mi gbogbo níwájú àwọn òrìṣà ní èmi ó kọrin ìyìn sí ọ Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ̀ èmi ó sì máa yin orúkọ Rẹ nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ àti òtítọ́ Rẹ nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ Rẹ ga ju orúkọ Rẹ lọ Ní ọjọ́ tí mo képè ọ́, ìwọ dá mi lóhùn, ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́, Olúwa , ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu Rẹ Nítòótọ́, wọn o máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa nítorí pé ńlá ní ògo Olúwa Bí Olúwa tilẹ̀ ga, ṣíbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ṣùgbọ́n agbéraga ní ó mọ̀ ní òkèrè réré Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di àyè ìwọ ó nà ọwọ́ Rẹ̀ si àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ ọ̀tún Rẹ yóò sì gbà mí Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé Olúwa , àánú Rẹ̀ dúró láéláé Má ṣe kọ isẹ́ ọwọ́ ara Rẹ̀ sílẹ̀ Sáàmù 139 Olúwa , ìwọ tí wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí Ìwọ mọ̀ ìjòkòó mi àti ìdìde mi, ìwọ mọ̀ ìrò mi ní ọ̀nà jnijin réré Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi kán àti idùbúlẹ̀ mi, gbogbo ọ̀nà mi sì di mímọ̀ fún ọ Nítorí ti kò si ọ̀rọ kan ní ahọ́n mi, kíyèsíi, Olúwa , ìwọ mọ̀ ọ́n pátapáta Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú, ìwọ sì fi ọwọ́ Rẹ lé mi Irú ìmọ̀ yìí ṣe ohun ìyanu fún mi jù ó ga, èmi kò le mọ̀ Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ní ọwọ́ ẹ̀mí Rẹ Tàbí níbo ní èmi yóò sáré kúrò níwájú Rẹ Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀ bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsí i, ìwọ wà níbẹ̀ Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀, kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin òkun Àní níbẹ̀ náà ni ọwọ́ Rẹ̀ yóò fà mí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ yóò sì dì mí mú Bí mo bá wí pé, ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọdọ̀ Rẹ ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ Nítorí ìwọ ní ó dá ọkàn mi ìwọ ní ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi Èmi yóò yìn ọ nítorí tẹ̀rùtẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi ìyanu ní isẹ́ Rẹ èyí nì ní ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọdọ̀ Rẹ, nígbà tí á dá mi ní ìkọ̀kọ̀, tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé Ojú Rẹ̀ ti rí ohun ara mi tí ó wà láìpé àti nínú ìwé Rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn sí, ní ojojumọ́ ni a ń dá wọn, nígbà tí ọ̀kan wọn kò tí i sí Ọlọ́run, ìrò inú Rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi, iye wọn ti pọ̀ tó! Èmi ibá kà wọ́n, wọ́n jù iyanrin lọ ní iye nígbà tí mo bá jí, èmi yóò wà lọ́dọ̀ Rẹ̀ ṣíbẹ̀ Ọlọ́run ibá jẹ pa àwọn ènìyàn búburú ní tòótọ́ nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ, àwọn ọ̀tá Rẹ ń pe orúkọ Rẹ ní aṣán! Olúwa , ǹjẹ́ èmi kò korìíra àwọn tó korìíra Rẹ Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ Èmi korìíra wọn ní àkótán èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi Ọlọ́run, wádíì mi, kí ó sì mọ ọkàn mí dán mi wò, kí ó sì mọ ìrò inú mi Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburú kan bá wà nínú mi kí ó sì fi ẹṣẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun Sáàmù 14 Asiwèrè wí nínú ọkàn Rẹ̀ pé, kò sí Ọlọ́run Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú kò sí ẹnìkan tí ó ṣe rere Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá lórí àwọn ọmọ ènìyàn bóyá ó le rí ẹni tí òye yé, ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́ kò sì sí ẹni tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn tí ó ń pa ènìyàn mí jẹ bí ẹníjẹ àkàrà tí wọn kò sì ké pe Olúwa Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù, nítorí Olúwa wà ní àwùjọ àwọn olódodo Ẹ̀yin olùṣe búburú ba èrò àwọn aláìní jẹ́, ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn Ìgbàlà àwọn Ísírẹ́lì yóò ti Síónì wá! Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn Rẹ̀ padà, jẹ́ kí Jákọ́bù kí ó yọ̀, kí inú Ísírẹ́lì kí ó dùn! Sáàmù 140 Olúwa , gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì, yọ mi lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà nì Ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn nígbàgbogbo ní wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò, oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ́ ní abẹ́ ètè wọn Olúwa , pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì ẹni tí ó ti pinnu Rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bá ọ̀nà wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi Olúwa , gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi Ọlọ́run Olúwa , agbára ìgbàlà mí, ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà Olúwa , máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún ún Má ṣe kún ọgbọ́n búburú Rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọn kí ó máa baà gbé ara wọn ga Sela Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi kákiri ni, jẹ́ kí ìka ètè ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná, sínú ọ̀gbun omi jínjìn, kí wọn kí ó má bà le dìde mọ́ Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹṣẹ̀ múlẹ̀ ní ayé ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró, yóò si ṣe ètò fun àwọn tálákà Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò máa fi ọpẹ́ fún orúkọ Rẹ àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú Rẹ Sáàmù 141 Olúwa , èmi ké pè ọ́ yára wá sí ọ̀dọ̀ mi Gbọ ohun mi, nígba ti mo ba n ké pè ọ́ Jẹ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú Rẹ bí ẹbọ tùràrí àti ìgbé ọwọ́ mi si okè rí bí i, ẹbọ àsàálẹ́ Mú kí ìsṣ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa kí o sọ̀ máa pa ilẹ̀kùn ètè mi mọ́ Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi, Láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ́ àdídùn wọn Jẹ́ kí olódodo lù mí ìṣeun ni ó jẹ́ jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi Tí kì yóò fọ́ mí ní orí Ṣíbẹ̀ àdúrà mi wá láí sí ìṣe àwọn olùṣe búburú A ó ju àwọn alákòóso sílẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ òkúta, àwọn ẹni búburú yóò kọ pé àwọn ọ̀rọ̀ mi dùn Egungun wa tàn kálẹ̀ ni ẹnu isà òkú, Bí ẹni tí ó ń tilẹ̀ tí ó sì ń la ilẹ̀, Ṣùgbọ́n ojú mi wá ẹ, Olúwa , Ọlọ́run nínú Rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe mú mi fún ikú Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tí wọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi, kúrò nínú ìdẹkùn tí àwọn olùṣe búburú ti dẹ sílẹ̀ Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn, nígbà tí èmi kọjá láìléwu Sáàmù 142 Èmi kígbe sókè sí Olúwa Èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú Rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú Rẹ̀ Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣààrẹ̀ nínú mi, ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀ Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì wò ó kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn fún mi èmi kò ní ààbò kòsí ẹni tí ó ṣe àníyàn fún ayé mi Èmi kígbe sí ọ, Olúwa èmi wí pe, ìwọ ni ààbò mi, ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè Fi etí sí igbe mi, nítorí tí èmi wà nínú àníìrètí gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi, nítorí wọ́n lágbára jù mi lọ Mú mi jáde kúrò nínú túbú, kí èmi lè máa yin orúkọ Rẹ Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò péjọ nípa mi nítorí iwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ba mi ṣe Sáàmù 143 Olúwa gbọ̀ àdúrà mi, fetísí igbe mi fún àánú nínú òtítọ́ àti òdodo Rẹ wá fún ìrànlọ́wọ́ mi Má ṣe mú ìránṣẹ́ Rẹ wá sí ìdájọ́, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láàyè tí ó ṣe òdodo níwájú Rẹ Ọ̀ta ń lé pa mi, ó fún mi pa mọ́ ilẹ̀ ó mú mi gbé nínú òkùnkùn bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́ Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi ọkàn mi tí ó wà nínú mi dààmú Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́ èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ Rẹ mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ Rẹ ti ṣe Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ òrùgbẹ Rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀ Sela Dámilóhùn kánkán, Olúwa ó Rẹ̀ ẹ̀mí mi Má ṣe pa ojú Rẹ mọ́ kúrò lára mi tàbí èmi yóò dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò Jẹ́ kí òwúrọ̀ mú ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí kì í kùnà wá fún mi, nítorí èmi ti gbẹ́kẹ̀ mi lé ọ Fí ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí, nítorí sí ọ ni èmi gbé ọkàn mi sókè Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa , nítorí èmi fí ara mi pamọ́ sínú Rẹ̀ Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ Rẹ, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi jẹ́ kí ẹ̀mí Rẹ dídára darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú Nítorí orúkọ Rẹ, Olúwa , sọ ayé mi di ààyè nínú òdodo Rẹ mú mi jáde nínú wàhálà Nínú ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀ta mi kúrò, run gbogbo àwọn ọ̀tá mi, nítorí èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ Sáàmù 144 Ìyìn sí Olúwa àpáta mi, ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun, àti ìka mi fún ìjà Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi, ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó tẹ́rí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi Olúwa , kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún-ún, tàbi ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa Rẹ̀ Ènìyàn rí bí èmi ọjọ́ Rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ Tẹ ọ̀run Rẹ ba, Olúwa , kí o sì sọ̀kalẹ̀ tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí, rú èéfín Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀ta ká ta ọfà Rẹ kí ó sì dà wọ́n rú Na ọwọ́ Rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga gbà mí kí ó sì yọ mí nínú ewu kúrò nínú omi ńlá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ Èmi yóò kọ orin túntún sí ọ Ọlọ́run lára ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá èmi yóò kọ orin sí ọ Sí ẹni tí ó fún àwọn ọba ní ìsẹ́gun, ẹni tí ó gba Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ pípanirun Gbàmí kí ó sì yọ mí nínú ewu kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì tí ẹnu wọn kún fún èké, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igi gbígbin tí ó dàgbà ni ìgba èwe wọn, àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin Àká wa yóò kún pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún, ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo kí ó má sí ìkọlù, kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn, kí ó má síi igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀, Ayọ̀ ni fún àwọn tí ẹni ti Ọlọ́run Olúwa ń ṣe Sáàmù 145 Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi Èmi yóò yin orúkọ Rẹ̀ láé àti láéláé Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́ èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Rẹ láé àti láéláé Títóbi ni Olúwa Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀ kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi Rẹ̀ Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ Rẹ dé ìran mìíràn wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára Rẹ Wọn yóò máa sọ ìyìn ọlá ńlá Rẹ tí ó lógo, èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu Rẹ Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára Rẹ tí ó ní ẹ̀rù èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá Rẹ̀ Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà rere Rẹ àti orin ayọ̀ òdodo Rẹ Olore òfẹ́ ni Olúwa àti aláàánú ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀, Olúwa dára sí ẹni gbogbo ó ní àánú lóri ohungbogbo tí ó dá Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni yóò máa yìn ọ́ Olúwa àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí Rẹ Wọn yóò sọ ògo ìjọba Rẹ wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára Rẹ, Kí gbogbo ènìyàn le mọ isẹ́ agbára rẹ̀ àti ola ńlá ìjọba Rẹ tí ó lógo Ìjọba Rẹ ìjọba ayérayé ni, àti ìjọba Rẹ wà ní gbogbo ìran-díran Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́, ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ Ìwọ sí ọwọ́ Rẹ ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà Rẹ̀ àti ìfẹ́ Rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́ Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ ṣẹ ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni búburú ní yóò parun Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ Rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé Sáàmù 146 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa , fi ìyìn fún Olúwa , ìwọ ọkàn mi Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè Ẹ má ṣe ní ìgbẹkẹ̀lé nínú àwọn ọmọ aládé, àní, ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀ Rẹ̀ Ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo Ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run Jákọ́bù ń ṣe ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ tí ìrètí Rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run Rẹ̀, Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn Olúwa , tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí láéláé Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa Olúwa , tú àwọn oǹdè sílẹ̀ Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran Olúwa , gbé àwọn tí a Rẹ̀ sílẹ̀ ga Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́ Olúwa jọba títí láé Ọlọ́run Rẹ, ìwọ Síónì, àti fún gbogbo ìran, Ẹ fi ìyìn fún Olúwa Sáàmù 147 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa nítorí ohun rere láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa, ó yẹ láti kọrin ìyìn síi Olúwa kọ́ Jérúsálẹ́mù O ko àwọn Ísírẹ́lì tí a lé sọnù jọ Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bajẹ́ sàn ó sì di ọgbẹ́ wọn Ó ka iye àwọn ìràwọ̀ ó sì pe ọ̀kọ̀ọkan wọn ní orúkọ Títóbi ní Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára òye Rẹ̀ kò sì ní òpin Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó Rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀ Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run Ó fi ìkuukù bo àwọ sánmọ̀ ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè Ó pèṣè oúnjẹ fún àwọn ẹranko àti fún awọn ọmọ àdàbà ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹsin bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin Olúwa ní ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀, sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú Rẹ̀ Yin Olúwa , ìwọ Jérúsálẹ́mù yin Ọlọ́run Rẹ̀, ìwọ Síónì Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ìbodè Rẹ̀ lágbára Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ Rẹ̀ nínú Rẹ Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè Rẹ̀ òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn Òun sì rán àṣẹ Rẹ̀ sí ayé ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sáré tete Ó fi sino fún ni bi irun àgùntàn ó sì fọ́n ìrì idídì ká bí eérú Ó rọ òjò yìnyín Rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú òtútù Rẹ̀ Ó rán ọ̀rọ̀ Rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀ ó mú kí afẹ́fẹ́ Rẹ̀ fẹ́ ó sì mú odò Rẹ̀ sàn Ó sọ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ di mímọ̀ fún Jákọ́bù àwọn òfin àti ìlànà Rẹ̀ fún Ísírẹ́lì Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀ èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ Rẹ̀ wọn ko mọ òfin Rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún Olúwa Sáàmù 148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ángẹ́lì Rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun Rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún un, oòrùn àti òṣùpá Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún un, ẹ̀yin ọ̀run àwọn ọ̀run gíga àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá ẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbi àti ẹ̀yin ibú òkun Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín ìdí omi àti àwọn ìkùùku, ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ Òkè ńlá àti gbogbo òkè kékèké, igi eléso àti gbogbo igi kédárì, Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ Àwọn ọba ayé àti ènìyàn áye gbogbo àwọn ọmọ aládé àti gbogbo àwọn onídájọ́ ayé, Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa nítorí orúkọ Rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá ògo Rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn Rẹ̀, ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún Olúwa Sáàmù 149 Ẹ fi ìyìn Olúwa Ẹ kọrin titun sí Olúwa Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́ Jẹ́ kí Ísírẹ́lì kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a jẹ́ kí àwọn ọmọ Síónì kí ó ní ayọ̀ nínú ọba wọn Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ Rẹ̀ jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá Rẹ̀ kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn àti idà olójú méjì ní ọ́wọ́ wọn Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀ èdè, àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn, Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn àti láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ irin de àwọn ọlọ́lá wọn Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ Rẹ̀ sí wọn èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún Olúwa Sáàmù 15 Olúwa , Ta ni yóò máa gbé nínú àgọ́ mímọ́ Rẹ Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ Rẹ Ẹni tí ń rìn déédéé tí ó sì ń sọ òtítọ́, láti inú ọkàn Rẹ̀ tí kò fi ahọ́n Rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò Rẹ̀ tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì Rẹ̀, ní ojú ẹni tí ènìyàn-kénìyàn di gígàn ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa , Ẹni tí ó búra sí ibi ara Rẹ̀ àní tí kò sì yípadà, tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí ni a kì yóò mì láéláé Sáàmù 150 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ Rẹ̀ Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run Rẹ̀ Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára Rẹ̀ Ẹ yìn ín fún títóbi Rẹ̀ tí ó tayọ̀ Ẹ fi ohùn ìpè, yìn ín Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín fi ohun èlò orin olokùn àti ìpè yìn ín Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè Ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa Ẹ fi ìyìn fún Olúwa Sáàmù 16 Pa mí mọ́, Ọlọ́run, nítorí nínú Rẹ ni ààbò mí wà Mo sọ fún Olúwa , ìwọ ni Ọlọ́run mi, lẹ́yìn Rẹ èmi kò ní ire kan Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé, àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà Ìṣòro àwọn wọ̀n ọn nì yóò pọ̀ síi àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi Olúwa , ni ìní mi tí mo yàn àti ago mi, ó ti pa ohun tí íṣe tèmi mọ́ Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára nítòótọ́ mo ti ní ogún rere Èmi yóò yin Olúwa , ẹni tí ó gbàmí ní ìyànjú ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀ Mo ti gbé Ọlọ́run ṣíwájú mi ní ìgbà gbogbo Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀ ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò, nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú iṣà òkú, tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ Rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́ Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní ìwájú Rẹ, pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ Sáàmù 17 Gbọ́, Olúwa , ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi fi etí sí igbe mi Tẹ́ti sí àdúrà mi tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ kí ojú Rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́ Ìwọ ti dán àyà mi wò, ìwọ sì yẹ̀ mí wò ní òru Bí ìwọ bá dán mi wò, ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀ Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu Rẹ èmi ti pa ara mi mọ́ kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà Rẹ ẹṣẹ̀ mi kì yóò yọ̀ Èmi ké pè ọ́, Olúwa , nítorí tí iwọ yóò dá mi lóhùn dẹ etí Rẹ sími kí o sì gbọ́ àdúrà mi Fi ìyanu ìfẹ́ ńlá Rẹ hàn ìwọ tí ó ń pamọ́ ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ àwọn tí ó wá ìsádi nínú Rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ta wọn Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú Rẹ fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji apá Rẹ Kúrò ní ọwọ́ ọ̀tá tí ó kọjú ìjà sí mi, kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀ta apani tí ó yí mi ká Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́, wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká, pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti sọ́ mi sílẹ̀ Wọn dà bí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ, àní bí Kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀ Dìde, Olúwa , dojúkọ wọ́n, Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà Rẹ Olúwa , nípa ọwọ́ Rẹ gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́ àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú Rẹ ní òdodo nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán Rẹ Sáàmù 18 Mo fẹ́ ọ, Olúwa , agbára mi Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi Òun ni àpáta ààbò àti agbára ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi Mo ké pe Olúwa , ẹni tí ìyìn yẹ fún, a ó sì gbàmí lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta à mi Ìrora ikú yí mi kà, àti ìsàn omi àwọn ènìyàn búbúrú dẹ́rùbà mí Okùn isà òkú yí mi ká, ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa Mo sunkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́ Láti inú tẹ́ḿpìlì Rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi ẹkún mi wá sí iwájú Rẹ̀, sí inú etí Rẹ̀ Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì pẹ̀lú, ìpìlẹ̀, àwọn òkè gíga sì sídìí wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú Èéfín ti ihò imú Rẹ̀ jáde wá Iná ajónirun ti ẹnu Rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú Rẹ̀ Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀ Ó gun orí kérúbù, ó sì fò ó ń rá bàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́ Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì Rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara Rẹ̀ ká kùrúkùrù òjò dúdú ní ojú ọ̀run Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú Rẹ̀, àwọ̀sánmà ṣíṣú dudu Rẹ kọja lọ pẹ̀lú yìnyín àti ẹyìn iná Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá Ohùn ẹni gíga jùlọ tí ń dún Ó ta àwọn ọfà Rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀ta náà ká, ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú A sì fi ìṣàlẹ̀ àwọn òkun hàn, a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé nípa ìbáwí Rẹ̀, Olúwa , nípa fífún èémí ihò imú Rẹ Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga ó sì dì mí mú Ó fà mí jáde láti inú omi jínjìn Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀ta mi alágbára, láti ọwọ́ àwọn ọ̀ta, ti ó lágbára jù fún mi Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi ṣùgbọ́n Olúwa ni alàtìlẹ́yìn mi Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá Ó gbà mí nítorí tí ó ní inúdídùn sí mi Olúwa ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi Nítorí mo ti pa ọ̀nà Olúwa mọ́ èmi kò ṣe búbúrú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi Gbogbo òfin Rẹ̀ ni ó wà níwájú mi èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà Rẹ̀ Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Rẹ̀ mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Olúwa san ẹ̀ṣan fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú Rẹ̀ Sí olóòótọ́ ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní olóòtọ́, sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi, Sí ọlọ́kan mímọ́, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́, ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní òǹrorò O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n o Rẹ̀ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀ Ìwọ, Olúwa , jẹ́ kí fìtílà mi kí ó máa tàn Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀ Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, èmi ṣare la ogun lọ pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà Rẹ̀ pé, a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwa òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa Ta ní àpátà bí kò ṣe Olúwa wa Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè ó sì mú ọ̀nà mi pé Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíja apá mi lè tẹ ọrùn idẹ Ìwọ fi àṣà ìṣẹ́gun Rẹ̀ fún mi, ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ gbé mí sókè àti ìwà ìpẹ̀lẹ́ Rẹ̀ sọ mi di alágbára àti ẹni ńlá Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ mi di ńlá ní ìṣàlẹ̀ mi, kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀ Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi èmi sì bá wọn èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n Èmi ṣá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde Wọ́n subú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní amùrè fún ogun náà ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀ta mí padà sí mi èmi sì pa àwọn tí ó kóríra mí run Wọ́n kígbé fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí yóò rànwọ́n lọ́wọ́ àní sí Olúwa , ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́ mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀ Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ́ èdè àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí Wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n gbọ́ gbàmí àwọn ọmọ àjèjì yóò fi ẹ̀tàn tẹríba fún mi Àyà yóò pá àlejò wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn Olúwa wà láàyè! Olùbùkún ni àpáta mi! Gbígbé ga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi, tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà ní abẹ́ mi, tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí Ìwọ gbé mi ga ju àwọn tí ó dìde sí mi lọ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí Títí láéláé èmi yóò máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, ìwọ Olúwa Èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ Rẹ Ó fún Ọba Rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá ó fi ìkáànú àìṣẹ̀tàn fún ẹni-àmì-òróró Rẹ̀, fún Dáfídì àti ìran Rẹ̀ títí láé Sáàmù 19 Àwọn òrun ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run Àwọ̀sánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀ Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́ wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́ Kò sí ohùn tàbí èdè níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé, ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run Ti o dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá Rẹ̀ wá Òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí o ń sáré ìje Ìjáde lọ Rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá àti àyíká Rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ Rẹ̀ kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore Rẹ̀ Pípé ni òfin Olúwa , ó ń yí ọkàn padà ẹ̀rí Olúwa dánilójú, ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n Ìlànà Olúwa tọ̀nà, ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn àṣẹ Olúwa ní mímọ́, ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́, ó ń faradà títí láéláé Ìdájọ́ Olúwa dájú òdodo ni gbogbo wọn Wọn ṣọ̀wọ́n ju gólùù lọ, ju góòlù tí o dára jùlọ wọ́n dùn ju oyin lọ, Àti ju afárá oyin lọ Nípa wọn ni a ti sí ìránṣẹ́ Rẹ̀ létí nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ Ta ni o lé mọ àṣìṣe Rẹ̀ Dáríjìn mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́ Wẹ ìrànsẹ́ Rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá Má ṣe jẹ kí wọn kí ó jọba lórí mi Nígbà náà ní èmí yóò dúró ṣinṣin, èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú Rẹ, Ìwọ Olúwa , àpáta mi àti Olùdáǹdè mi Sáàmù 2 Èéṣe tí àwọn orílẹ̀ èdè fi ń dìtẹ̀, àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkísí asán Àwọn ọba ayé péjọ pọ̀ àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀ sí Olúwa àti sí Ẹni àmì òróró Rẹ̀ Wọ́n sọ pé, Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já, kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà Nígbà náà ni ó bá wọn wí ní ìbínú Rẹ̀ ó sì dẹ́rùba bà wọ́n ní ìrunú Rẹ̀, ó wí pé, Èmi ti fi ọba mi sí ipò lórí Síónì, òkè mímọ́ mi Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa Ó sọ fún mi pé, Ìwọ ni ọmọ mi lónìí, èmi ti di baba Rẹ Béèrè lọ́wọ́ mi, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀ èdè di ìní Rẹ, òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún Rẹ Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn ìwọ yóò sì rún wọn wómú wómú bí ìkòkò amọ̀ Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé Ẹ ṣin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú kí ó má ba à payin run ní ọ̀nà yin, nítorí ìbínú Rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi i ṣe ibi ìsádi wọn Sáàmù 20 Kí Olúwa kí ó gbóhùn Rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú kí orúkọ Ọlọ́run Jákọ́bù kí ó dáàbòbò ọ́ Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́ kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Síónì wá Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ ọrẹ Rẹ kí ó sì gba ẹbọ sísun un Rẹ Sela Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn Rẹ kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ Rẹ ṣẹ Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa Kí Ọlọ́run kí ó mú gbogbo ìbéèrè Rẹ̀ ṣẹ Nisinsìnyí, èmi mọ̀ wí pé Olúwa pa ẹni-àmí-òróró Rẹ̀ mọ́ yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ Rẹ̀ wá pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin, ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọn sì ṣubú, ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin Olúwa , fi ìṣẹ́gun fún ọba! Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè! Sáàmù 21 Áà! Olúwa , Ọba yóò yọ̀ nínú agbára Rẹ, àti ní ìgbàlà Rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó! Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn Rẹ̀ fún un, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu Rẹ̀ Sela Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí O ní ọwọ́ Rẹ, ìwọ sì fi fún un, àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé Ògo Rẹ̀ pọ̀ nípaṣẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún-un ìwọ́ sì jẹ́ kí iyì ọlánlá Rẹ̀ wà lára Rẹ Dájúdájú ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún-un ìwọ́ sì mú inú Rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u Rẹ̀ Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa nípaṣẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá ògo tí kì í kùnà kì yóò sípò padà Ọwọ́ Rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀ta a Rẹ rí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ yóò wà àwọn tí o kóríra Rẹ rí Nígbà tí ìwọ bá yọ ìwọ yóò mú wọn dàbí ìnà ìléru Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú Rẹ̀, àti pé iná Rẹ̀ yóò jó wọn run Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀, àti irú ọmọ wọn kúrò láàrin àwọn ọmọ ènìyàn Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ wọ́n sì ń pète ìwà-ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà Gbígbéga ni ọ Olúwa , nínú agbára Rẹ a ó kọrin, a ó yín agbára a Rẹ̀ Sáàmù 22 Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀ Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là, àní sí igbe àwọn asọ̀ mi Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn àti ní òru èmi kò dákẹ́ Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ ẹni mímọ́ ni ìwọ ẹni tí ó tẹ ìyìn Ísírẹ́lì dó Àwọn babańlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú un Rẹ wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójú tì wọ́n Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́ kì í sì í ṣe ènìyàn mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn ẹlẹ́yà àwọ́n ènìyàn Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí i wọn pé Ó gbẹkẹ Rẹ̀ lé Olúwa jẹ́ kí Olúwa gbà á là Jẹ́ kí ó gbà a là, nítorí pé ó ni ayọ̀ nínú Rẹ̀ Ṣíbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá nígbà tí ìyá a mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi Má ṣe jìnnà sími, nítorí pé ìyọnu sún mọ́ tòsí kò sì sí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká àwọn màlúù alágbára Báṣánì rọ̀gbà yí mi ká wọ́n ya ẹnu wọn, si mi bí i kìn-nìún tí ń dọdẹ kiri tí ń ké ramúramù A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé Rẹ̀ Ọkàn mi sì dàbí i ìda tí ó yọ́ láàrin inú un mi Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mí sì ti lẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú Àwọn ajá yí mi ká ọwọ́ àwọn ènìyàn ibi ti ka mi mọ́, Wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́ṣẹ̀ Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa , má ṣe jìnnà sí mi Áà Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wa fún àtìlẹ́yìn mi! Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà, àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ kìnnìún Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré Èmi yóò kéde orúkọ ọ̀ Rẹ láàrin arákùnrin àti arábìnrin mi nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́ Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa , ẹyìn-ín! Gbogbo ẹ̀yin ìran Jákọ́bù, ẹ fi ògo fún-un! ẹ dìde fún-un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú ọmọ Ísírẹ́lì! Nítorí pé òun kò ṣááta, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra ìpọ́njú àwọn tí a ni lára kò sì fi ojú Rẹ̀ pamọ́ fún mi ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é Lati ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ẹsẹ̀ ìyìn mi nínú àwùjọ ńlá yóò ti wá ẹ̀jẹ́ Rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù Rẹ̀ talákà yóò jẹ yóò sì yó àwọn tí n wá Olúwa yóò yin jẹ́ kí ẹ̀mí Rẹ̀ wà láàyè títí ayárayé! Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí wọn yóò sì yípadà sí Olúwa , àti gbogbo ìdílé orílẹ̀ èdè ni wọn yóò jọ́sìn níwájú Rẹ̀, Nítorí ìjọba ni ti Olúwa Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀ èdè Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àṣè, wọn yóò sì sìn gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájúu Rẹ̀ àti ẹni ti kò le pa ọkàn ara Rẹ̀ mọ́ ni ààyè Irú ọmọ Rẹ̀ yóò sìn-in a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ nípa Olúwa , Wọn yóò polongo òdodo Rẹ̀ sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí, wí pé òun ni ó ṣe èyí Sáàmù 23 Olúwa ni Olùsọ́ àgùntàn mi, èmi kì yóò ṣe aláìní Ó mú mi dùbúlẹ̀ síbi pápá oko tútù Ó mú mi lọ síbi omí dídákẹ́ rọ́rọ́ Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò Ó mú mi lọ sí ọ̀nà ododo nítorí orúkọ Rẹ̀ Bí mo tílẹ̀ ń rìn Láàrin àfonífojì òjiji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan nítorí ìwọ wà pẹ̀lú ù mi ọ̀gọ Rẹ àti ọ̀pá à Rẹ wọ́n ń tù mi nínú Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú ù mi ní ojú àwọn ọ̀tá à mi ìwọ ta òróró sí mi ní orí ago mí sì kún àkún wọ́ sílẹ̀ Nítòótọ, ire àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo, èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa títí láéláé Sáàmù 24 Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún Rẹ̀, ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú Rẹ̀ Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ Rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkun ó sì gbée kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi Ta ni yóò gun òrí òkè Olúwa lọ Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ Rẹ̀ Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn Rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa , àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà Rẹ̀ Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí Rẹ̀, tí ń ṣe àfẹ́rí Rẹ̀, Ọlọ́run Jákọ́bù Sela Ẹ gbé orí yín sókè, Áà! Ẹ̀yin ọ̀nà Kí á sì gbe yín sókè, áà! Ẹyin ilẹ̀kùn ayérayé! Kí ọba ògo le è wọlé Ta ni ọba ògo náà Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le, Olúwa gan-an, tí o lágbára ní ogun Gbé orí yín sókè, áà! Ẹ̀yin ọ̀nà Kí a sì gbé yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, Kí ọba ògo le è wọlé wá Ta ni ọba ogo náà Olúwa àwọn ọmọ ogun Òun ni ọba ògo náà Sela Sáàmù 25 Olúwa , ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀ta mi ó yọ̀ mí Ẹni tí ó dúró tì ọ́ ojú kí yóò tìí àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí ni kí ojú kí ó tì Fi ọ̀nà Rẹ hàn mí, Olúwa , kọ mi ní ipa tìrẹ ṣe amọ̀nà mi nínú ọ̀títọ́ ọ Rẹ, kí ò si kọ́ mi, Nítoríi ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́ Rántí, áà! Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ̀ ńlá, torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́ Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi tàbí ìrékọjáà mi gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ Rẹ̀ rántíì mi nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa nítorí náà ó kọ́ àwọn ẹlẹ́sẹ̀ ni ọ̀nà náà Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára, ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà Rẹ̀ Gbogbo ipa ọ̀nà Olúwa ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin, fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí Rẹ̀ mọ́ Nítorí orúkọ Rẹ̀, áà! Olúwa , dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn mí, nítorí tí ó tóbi Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa Yóò kọ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà, àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u Rẹ̀ ó sọ májẹ̀mú Rẹ̀ di mímọ̀ fún wọn Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa , nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà Yípadà sími, kí o sì ṣe oore fún mi nítorí pé mo nìkàn wà, mo sì di olùpọ́njú Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú ù mi Kíyèsí ìjìyà àti wàhálà mi, kí o sì darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn Kíyẹ̀sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi, tí wọn kórìírá a mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀ Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú, nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́ nítorí pé mo dúró tì ọ́ Ra Ísírẹ́lì padà, Ìwọ Ọlọ́run, nínú gbogbo ìṣòro Rẹ̀! Sáàmù 26 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa , nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi, mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀ Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa , kí o sì dán mi wò, dán àyà àti ọkàn mi wò Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi, èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ Rẹ Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìsòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé Èmi ti kórìírá àwùjọ àwọn ènìyàn búburú èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ Rẹ ká Olúwa Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́, èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ Áà Olúwa , èmí ń fẹ́ ilé Rẹ ní bi tí ìwọ ń gbé, àní níbi tí àgọ́ ọlá Rẹ̀ wà Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ, Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́ rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa Sáàmù 27 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi ta ni èmi yóò bẹ̀rù Olúwa ni ibi olódì ẹ̀mí mi, ta ni ẹni tí èmi yóò bẹ̀rù Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi láti jẹ ẹran ara mi, àní àwọn ọ̀ta mi àti àwọn abínúkú ù mi, wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú Bí ọmọ ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi, ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi, nínú èyí ni ọkàn mi yóò le Ohun kan ni mo bèèrè nípasẹ̀ Olúwa , òun ni èmi yóò máa wá kiri kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi kí ó le kíyèsí ẹwà Olúwa , kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹ́ḿpìlì Rẹ Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ Rẹ̀ níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ Rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́ yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta Ní ìsinsin yìí a ti gbé orí mi sókè ga ju ti àwọn ọ̀tá a mi lọ tí ó yí mí ká èmi yóò rúbọ nínú àgọ́ Rẹ ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀ èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa Gbọ́ ohùn mi nígbà tẹ́mi báà ń pè, Áà Olúwa , ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn Wá, ọkàn mi wí pé, wá ojú u Rẹ̀ Ojú ù Rẹ, Olúwa , ni èmí ń wá, Má ṣe fi ojú Rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi, má ṣe fi ìbínú ṣá ìránṣẹ́ Rẹ tì ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi, Má ṣe ju mi sílẹ̀, má si ṣe kọ̀ mí, áà Ọlọ́run ìgbàlà mi Bí ìyá àti bàbá bá kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí Kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ, Olúwa , kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú nítorí àwọn ọ̀tá mi Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀ta mi lọ́wọ́, nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi, wọ́n sì mí ìmí ìkà Èmi ní ìgbàgbọ́ pé èmi yóò rí ìre Olúwa ní ilẹ̀ alààyè Dúró de Olúwa kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le àní dúró de Olúwa Sáàmù 28 Ìwọ Olúwa , mo képe àpáta mi Má ṣe kọ eti dídi sí mi Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi, èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú, bí mo ṣe ń ké pé ọ́ fún ìràn lọ́wọ́, bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè sí ibi mímọ́ Rẹ jùlọ Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti, pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn Ṣan ẹ̀ṣan wọn gẹ́gẹ́ bí isẹ́ wọn àti fún iṣẹ́ ibi wọn gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn kí o sì san ẹ̀ṣan wọn bí ó ti tọ́ Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, tàbí àwọn isẹ́ ọwọ́ Rẹ̀ òun ó rún wọn wọlẹ̀ kò sì ní tún wọn kọ́ mọ́ Alábùkún fún ni Olúwa ! Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi Olúwa ni agbára mi àti aṣà mi nínú Rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́ ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀ àni pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn Rẹ̀ òun ni odi ìgbàlà àwọn àyànfẹ́ẹ Rẹ̀ Ìwọ gba àwọn ènìyàn Rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún Rẹ di olùsọ́ àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé Sáàmù 29 Ẹ fi fún Olúwa , ẹ̀yin ìran ọ̀run, Ẹ fi fún Olúwa , ògo àti agbára Fi fún Olúwa , àní ògo orúkọ Rẹ̀ sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ Ohùn Olúwa ré àwọn omi kọjá Ọlọ́run ògo sán àrá, Olúwa náà, alágbára ń bẹ lóríi omi púpọ̀ Ohùn Olúwa ní agbára ohùn Olúwa kún fún ọláńlá Ohùn Olúwa fọ́ igi kédárì Olúwa náà ló fọ́ igi kédárì Lébánónì Ó mú Lébánónì fo bí i ọmọ màlúù, àti Síríónì bí ọmọ àgbáǹréré Ohùn Olúwa ń ya bí ọwọ́ iná mọ̀nà Ohùn Olúwa ń mi ihà Olúwa mi ihà Kádéṣì Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀rín bí ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòòhò àti nínú tẹ́ḿpìlì Rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé Ògo! Olúwa jókòó, Ó sì jọba lórí ìṣàn omi Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba títí láéláé Kí Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ bùkún àwọn ènìyàn Rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà Sáàmù 3 Àdúrà Dáfídì Nígbà Tí ó Ṣá Fún Ọmọ Rẹ̀ Ábúsálómù Olúwa , báwo ni àwọn ọ̀ta mi ṣe pọ̀ tó! Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé Ọlọ́run kò ní gbà á là Ṣùgbọ́n ìwọ ni àṣà yí mi ká, Olúwa iwọ fi ogo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè Olúwa ni mo kígbe sókè sí, ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ Rẹ̀ wá Èmi dúbùú lẹ̀, mo sì sùn mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká Dìde, Olúwa ! Gbà mí, Ọlọ́run mi! Lu gbogbo àwọn ọ̀ta mi ní àgbọ̀n kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá Kí ìbùkún Rẹ̀ wà lóri àwọn ènìyàn Rẹ̀ Sela Sáàmù 30 Èmi yóò kókìkíì Rẹ, Olúwa , nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀ta mi kí ó yọ̀ mí Olúwa Ọlọ́run mi, èmí ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́ ìwọ sì ti wò mí sàn Olúwa , ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má baà lọ sínú ihò Kọ orin ìyìn sí Olúwa , ẹ̀yin olódodo kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ Rẹ̀ mímọ́ Nitorí pé ìbínú Rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀, ojúrere Rẹ̀ wà títí ayeraye Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́, Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀ Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé, a kì yóò sí mi nípò padà Nípa ojúrere Rẹ̀, Olúwa , ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára ìwọ pa ojú Rẹ mọ́, àyà sì fò mí Sí ọ Olúwa , ni mo képè àti sí Olúwa ni mo sunkún fún àánú Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi, nínú lílọ sí ihò mi Eruku yóò a yìn ọ́ bí Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo Rẹ Gbọ́, Olúwa , kí o sì ṣàánú fún mi ìwọ Olúwa , jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi Ìwọ ti yí ìkáànú mi di ijó fún mi ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí, nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí ó má sì ṣe dákẹ́ Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé Sáàmù 31 Nínú Rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí gbà mí nínú òdodo Rẹ Tẹ́ etí Rẹ sí mi, gbà mí kíákíá jẹ́ àpáta ààbò mi, jẹ́ odi alágbára láti gbà mí Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi, nítorì orúkọ Rẹ máa ṣe ìtọ́ mi tọ́ mi kí o sì ṣe amọ̀nà mi Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi, nítorí ìwọ ni ìsádi mi Ní ọwọ́ Rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé ìwọ ni ó tí rà mí padà, Olúwa , Ọlọ́run òtítọ́ Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fi yè sí òrìṣà tí kò níye lórí ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá Rẹ, nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú Pẹ̀lú ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi àyè ńlá Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa , nítorí mo wà nínú ìpọ́njú ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn, ọkàn àti ara mi pẹ̀lú Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn agbára mi ti kùnà nítorí òṣì mi, egungun mi sì ti rún dànù Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn ọ̀tá mi gbogbo, pẹ̀lú pẹ̀lú láàrin àwọn aládùúgbò mi, mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú Èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́ Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi láti gba ẹ̀mi mi Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa Mo sọ wí pé, Ìwọ ní Ọlọ́run mi Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ Rẹ gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi àti àwọn onínúnibíni Jẹ́ kí ojú ù Rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìrànṣẹ́ Rẹ lára Gbà mí nínú ìfẹ́ẹ̀ Rẹ tí ó dúró ṣinṣin Má ṣe jẹ́ kí á fi mí sínú ìtijú, Olúwa nítorí pé mo ké pè ọ́ jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo Báwo ni títóbi oore Rẹ̀ ti pọ̀ tó, èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ, èyí tí ìwọ rọ̀jò Rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọ́ se ibi ìsádi wọn Ní abẹ́ ibòji iwájú Rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn ní ibùgbé Rẹ o mú wọn kúrò nínú ewu kúrò nínú ìjà ahọ́n Olùbùkún ni Olúwa , nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yí ká Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi, A gé mi kúrò ní ojú Rẹ! Ṣíbẹ̀ ìwọ́ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ Ẹ fẹ́ Olúwa , gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Rẹ̀ mímọ́! Olúwa pa olódodo mọ́, ó sì san-án padà fún agbéraga ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa Sáàmù 32 Ìbùkún ni fún àwọn tí a dárí ìrékọjá wọn jìn, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀ Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ sí i lọ́rùn àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi di gbígbó dànù nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́ Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru ọwọ́ Rẹ̀ wúwo sími lára agbára mi gbẹ tán gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn Sela Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ àti pé èmi kò sì fi àìsòdodo mi pamọ́ Èmi wí pé, Èmi yóò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa , ìwọ sì dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn mí Sela Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ ní ìgbà tí a le ri ọ nitòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè, wọn kì yóò le dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀ Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka Sela Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ Rẹ lé ọ̀nà ìwọ yóò rìn èmi yóò máa gbà ọ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ Má ṣe dàbí ẹsin tàbí ìbaka, tí kò ní òye ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀, kí wọn má ba à sún mọ́ ọ Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká Ẹ yọ̀ nínú Olúwa , kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin Sáàmù 33 Ẹyọ̀ nínú Olúwa , ẹ̀yin olódodo ìyín si yẹ fún ẹnidídúró ṣinṣin Ẹyin Olúwa pẹ̀lú dùùrù ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i Ẹ kọ orin tuntun sí i ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin síi, pẹ̀lú ariwo ńlá Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin, gbogbo iṣẹ́ Rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́ Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa Nípaṣẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu Rẹ̀ Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò ó sì fi ibú sí ilé ìṣúra gbogbo Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù Rẹ̀ Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀ ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀ èdè wá sí asán ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákìí Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé, àní ìrò inú Rẹ̀ láti ìrandíran ni Ìbùkún ni fún orílẹ̀ èdè náà Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀, àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní Rẹ̀ Olúwa wò láti ọ̀run wá Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn Níbi tí ó ti jókòó lóríi ìtẹ́ Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà, ó sì kíyèsí ìṣe wọn A kò gba ọba kan là nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá Rẹ̀ Ohun asán ni ẹṣin fún ìsẹ́gun bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá Rẹ̀ gba ni sílẹ̀ Wòó ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀, àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ Rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin, Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú àti láti pa wọ́n mọ́ láàyè lọ́wọ́ ìyàn Ọkàn wa dúró de Olúwa òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti aṣà wa Ọkàn wa yọ̀ nínú Rẹ̀, nítorí pé, àwa gba orúkọ mímọ́ Rẹ̀ gbọ́ Kí àánú Rẹ, Olúwa , kí ó wà lára wa, àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú Rẹ Sáàmù 34 Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo ìyìn Rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ Rẹ̀ lékè Èmi wá Olúwa , ó sì dá mi lóhùn Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo Wọ́n wòó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn ojú kò sì tì wọ́n Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn Rẹ̀ ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú Rẹ̀ Ángẹ́lì Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ ká ó sì gbà wọ́n Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú Rẹ̀ Ẹ bẹ̀rù Olúwa , ẹ̀yin ènìyàn Rẹ̀ mímọ́, nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa Taa ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀ kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere Pa ahọ́n Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi àti ètè Rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere wá àlàáfíà, kí o sì lépa Rẹ̀ Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo etí i Rẹ̀ sì sí sí ẹkún wọn Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀ Nígbà tí Olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn Olúwa sún mọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ó sì gba irú àwọn tí i ṣe oníròra ọkàn là Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀, ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo Rẹ̀ Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́ kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn Ibi ni ó mú ikú ìkà wá, àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ padà kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀le tí yóò jẹ̀bi Sáàmù 35 Olúwa , gbógun ti àwọn tí ń gbógun tì mí kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà! Di aṣà àti àpáta mú, kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi! Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi sọ fún ọkàn mi pé, Èmi ni ìgbàlà Rẹ Kí wọn kí ó dààmú, kí a sì ti àwọn tí ń lépa ọkàn mi lójú kí a sì mú wọn padà, kí a sì dààmú àwọn tí ń gbérò ìpalára mi Jẹ́ kí wọn dà bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́, kí ángẹ́lì Olúwa kí ó máa lé wọn kiri Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó sókùnkùn kí ó sì máa yọ́, kí áńgẹ́lì Olúwa kí ó máa lépa wọn! Nítorí pé, ní àìnídìí ní wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi, ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò fún ọkàn mi Jẹ́ kí ìparun kí ó wá sí orí wọn lójijì Àwọ̀n Rẹ̀ tí ó dẹ pamọ́, kí ó mú àwọn tìkálára wọn kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara Rẹ̀ Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Olúwa , àní ayọ̀ ńlá nínú ìgbàlà Rẹ̀ Gbogbo egúngún mi yóò wí pé, ìwọ Olúwa , ta ni ó dà bí i Rẹ̀ O gba talákà là lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù wọ́n lọ, talákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde wọ́n bi mi léèrè àwọn ohun tí èmi kò mọ̀ Wọ́n fi búburú san ire fún mi láti sọ ọkàn mi di òfo Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀ mo fi ààwẹ̀ pọ́n ara mi lójú Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi bí i ẹni wí pé ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ní wọ́n mo ń lọọ́ kiri bí ẹni tí ń sọ̀fọ̀ fún ìyà Rẹ̀, tí o tẹríba nínú ìbànújẹ́ Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n kó ara wọn jọ wọ́n sì yọ̀, wọ́n kó ara wọn jọ sí mi àní àwọn tí èmi kò mọ̀ wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́ Àwọn àgàbàgebè ń ṣe yẹ̀yẹ́ mi ṣíwájú àti sí wájú síi wọ́n pa eyín wọn keke sí mi Yóò ti pẹ́tó, ìwọ Olúwa , tí ìwọ yóò máa wò wọ́n lọ Yọ mí kúrò nínú ìparun wọn àní ẹ̀mí i mi kúrò lọ́wọ́ kìnnìún Nígbà náà ni èmi yóò sọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń ṣe ọ̀tá mi kí ó yọ̀ lórí ì mi, tàbí àwọn tí ó kórìírá mi ní àìní dí máa sẹ́jú sí mi Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà, ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi wọ́n sọ wí pé, Áà! Áà! Ojú wa sì ti rí i Ìwọ́ ti ríi Ìwọ Olúwa Má ṣe dákẹ́! Ìwọ Olúwa , Má ṣe jìnnà sí mi! Jí dìde! Ru ara Rẹ̀ sókè fún ààbò mi, fún ìdí mi, Ọlọ́run mi àti Olúwa mi! Dá mi láre, ìwọ Olúwa , Ọlọ́run mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo Rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí wọn kí ó yọ̀ lórí mi! Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, Áà! Àti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́ Má ṣe jẹ kí wọn kí ó wí pé, a ti gbé e mì Kí ojú kí ó tì wọ́n, lí wọn kí ó sì dààmú pọ̀, tí ń yọ̀ sí ìyọnu mi kí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọ tí ń gbéraga sí mi Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi fó fún ayọ̀ àti ìdùnnú, kí wọn máa sọ ọ́ titi lọ, pé gbígbéga ni Olúwa sí àlàáfíà ìránṣẹ Rẹ̀ Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo Rẹ, àti ìyìn Rẹ ní gbogbo ọjọ́ Sáàmù 36 Ìrékọjá sọ̀rọ̀ sí ènìyàn búburú jinlẹ̀ nínú ọkàn wọn Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú ojú wọn Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òun ẹ̀tàn wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀ Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀ Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ Rẹ, ìwọ Olúwa , ó ga dé ọ̀run, òtítọ́ ọ̀ Rẹ ga dé àwọ̀sánmà Òdodo Rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run, àwọn ìdájọ́ Rẹ dàbí ibú ńlá ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa Báwo ni ìṣeun ìdúróṣinṣin ìfẹ́ Rẹ ti tó! Ọlọ́run! Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjijì ìyẹ́ Rẹ Àsè ilé Rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú-dídùn Rẹ Nítorí pé pẹ̀lú ù Rẹ ni orísun ìyè wà nínú ìmọ́lẹ̀ Rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀ Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ Rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́ àti ìgbàlà Rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn! Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi, kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ni ipò Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé subú sí a Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde! Sáàmù 37 Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlàra nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé wọn yóò gbẹ bí koríko, wọn yóò sì Rẹ̀ dànù bí ewéko tútù Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa , kí o sì máa ṣe rere torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò Rẹ̀ ṣe inú dídùn sí Olúwa òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú Rẹ̀ Fi ọ̀nà Rẹ lé Olúwa lọ́wọ́ gbẹ́kẹ̀lée pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é Yóò sì mú kí òdodo Rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ, àti ìdájọ́ Rẹ̀ bí ọ̀sán gangan Ìwọ dákẹ́ jẹ́ ẹ́ níwájú Olúwa , kí o sì fi sùúrù dúró dè é má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn, nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkannú sílẹ̀ Má ṣe ṣe ìkanra, nítorí pé ó gbéni sí búburú pẹ̀lú Nítorí pé á ó gé àwọn ènìyàn búburú kúrò, Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà Ṣíbẹ̀ nígbà díẹ̀ síi,, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́ nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò Rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀ Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà, wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà Ènìyàn búburú di rìkísí sí olóòtọ́, wọ́n sì pa ẹyín wọn keke sí wọn Ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rin-un sí àwọn ènìyàn búburú, nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀ Ènìyàn búburú fa idà yọ, wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn, láti sọ talákà àti aláìní kalẹ̀, láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ, àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́ Ohun díẹ̀ tí olódodo ní sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú Nítorí pé a ó ṣẹ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn adúró ṣinṣin, àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi, àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé, àwọn ọ̀ta Olúwa yóò dà bí ẹwà oko tútù wọn fò lọ bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san-án padà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa fi fún ni Nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà, àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, o si ṣe inú dídùn sí ọ̀nà Rẹ̀ Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátapáta, nítorí tí Olúwa di ọwọ́ Rẹ̀ mú Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmí sì dàgbà ṣíbẹ̀ èmi kò ì tíi rí ki a kọ olódodo ṣílẹ̀, tàbí kí irú ọmọ Rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni a sì máa bùsí i fún ni Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere nígbà náà ni ìwọ gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́, kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ sílẹ̀ Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ní a ó ké kúrò Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà, yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ahọ́n Rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́ Òfin Ọlọ́run Rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn àwọn ìgbẹ́sẹ̀ Rẹ̀ kì yóò yẹ̀ Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo, Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi, nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ Rẹ̀ Dúró de Olúwa , kí o sì má a pa ọ̀nà Rẹ̀ mọ́, yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà Nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri Èmí ti rí ènìyàn búburú tí n hu ìwà ìkà, ó sì fi ara Rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá Ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan síi ó kọjá lọ, sì kíyèsí, kò sì sí mọ́ bi ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri Má a kíyèsí ẹni pípé, kí o sì wo adúró ṣinṣin, nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ní a ó parun papọ̀ ìran àwọn ènìyàn búburú ní a ó gé kúrò Ìgbàlà àwọn adúró ṣinṣin wa láti ọ̀dọ̀ Olúwa òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e Sáàmù 38 Olúwa Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú Rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú Rẹ̀ Nítorí tí ọfà Rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin, ọwọ́ Rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀ Kò sí ibi yíyè ní ara à mi nítorí ìbínú Rẹ kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi Nítorí àìṣedédé mi ti borí mi mọ́lẹ̀ wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́ nítorí òmùgọ̀ mi Èmi ń jòwèrè orí mi tẹ̀ ba gidigidi èmi ń sọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́ Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná ti ń jó ni kò sì sí ibi yíyè ní ara mi, Ara mi hù, a sì wó mi jégéjégé mo ké rora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi Olúwa , gbogbo a áyun mi ń bẹ níwájú Rẹ ìmí ẹ̀dùn mi kò sá pamọ́ fún ọ Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀ bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi, àwọn alábàágbé é mi, dúró lókèèrè Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun, wọ́n sì ń gbérò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́ Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀ àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀ Ní tòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́ràn, àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa , ìwọ ni mo dúró dè ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn Nítorí tí mo gbàdúrà, Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi Nítorí tí mo ti ṣe tán láti ṣubú, ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láì ní ìdí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìírá mi lọ́nà òdì Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi àwọn ni ọ̀ta mi nítorí pé mò ń tọ ire lẹ́yìn Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa ! Ọlọ́run mi Má ṣe jìnnà sí mi Yára láti ràn mí lọ́wọ́, Olúwa , Olùgbàlà mi Sáàmù 39 Mo wí pé, èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀ èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi Mo fi ìdákẹ́ ya odi mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ síi Àyà mi gbóná ní inú mi, nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, ina ràn nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀ Olúwa , jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi, àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín Ìwọ ti ṣe ayé mi bí ìbú àtẹ́lẹwọ́, ọjọ́ orí mi sì dàbí asán ní iwájú Rẹ Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú ìjókòó rere Rẹ̀ jásí asán pátapáta Sela Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ, wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, Olúwa , kín ni mo ń dúró dè Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Rẹ Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn àwọn ènìyàn búburú Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́ èmi kò sì ya ẹnu mi, nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é Mú ìnà Rẹ̀ kúrò ní ara mi èmí ṣègbé tán nípa ìlù ọwọ́ Rẹ Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀ fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ a mú ẹwà Rẹ parun bí kòkòrò aṣọ nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa , kí o sì fetí sí igbe mi kí o má ṣe di etí Rẹ sí ẹkún mi nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ Rẹ àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára, kí èmi tó lọ kúrò níhín-ín yìí, àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí Sáàmù 4 Àdúrà Fún Ìrànlọ́wọ́ Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́, iwọ Ọlọ́run òdodo mi, Fún mi ní ìdánídè nínú ìpọ́njú mi ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹyin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ́ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá Ọlọ́run èké Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo ṣọ́tọ̀ fún ara Rẹ̀ Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀ Nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín, ẹ bà ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́ Ẹ rú ẹbọ òdodo kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, Ta ni yóò ṣe rere fún wá Olúwa , Jẹ́ kí ojú Rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára, Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà, nítorí ìwọ nìkan, Olúwa , ni o mú mi gbé láìléwu Sáàmù 40 Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi Ó fà mí yọ gòkè láti inú ihò ìparun, láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta, ó sì jẹ́ kí ìgbesẹ̀ mi wà láìfòyà Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu, àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa Ọ̀pọ̀ yóò ríi wọn yóò sì bẹ̀rù, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n ọn-nì tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga, tàbí àwọn tí ó yapa lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn isẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn, wọn ju ohun tí ènìyàn leè kà lọ Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ìwọ ti sí mi ní etí Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò bèèrè Nígbà náà ni mo wí pé, Èmi nìyí nínú ìwé kíkà nì a kọ ọ nípa temí wí pé Mo ní inú dídùn láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi Òfin Rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà láàrin àwùjọ ńlá wòó, èmi kò pa ètè mí mọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀, ìwọ Olúwa Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi, èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà Rẹ̀ èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti òtítọ́ Rẹ̀ mọ́ kúrò láàrin àwọn ìjọ ńlá Ìwọ má ṣe, fa àánú Rẹ̀ tí ó rọnú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ àti òtítọ́ Rẹ kí ó máa pa mí mọ́ títí ayérayé Nítorí pé àìníye ibi ni ó yí mi káàkiri, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi, títí tí èmi kò fi ríran mọ́ wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, àti wí pé àyà mí ti kùnà Jẹ́ kí ó wù ọ́, ìwọ Olúwa , láti gbà mí là Olúwa , yára láti ràn mí lọ́wọ́ Gbogbo àwọn wọ̀nnì ni kí ojú kí ó tì kí wọn kí ó sì dààmú àwọn tí ń wá ọkàn mi láti parun jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn ki á sì dójú tì wọ́n, àwọn tí n wá ìpalára mi Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, Áà! Áá! ó di ẹni àfọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtijú wọn Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ kí ó máa yọ̀ kí inú wọn sì máa dùn sí ọ kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà Rẹ kí o máa wí nígbà gbogbo pé, Gbígbéga ni Olúwa ! Bí ó ṣe ti èmi ni, talákà àti aláìní ni èmi, ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi àti ìgbàlà mi Má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́, ìwọ Ọlọ́run mi Sáàmù 41 Ìbùkùn ni fún ẹni tí ó ń rò ti aláìní Olúwa yóò gbà á ni ìgbà ìpọ́njú Olúwa yóò dààbò bòó yóò sí pa ọkàn Rẹ̀ mọ́ yóò bùkún fún-un ni orí ilẹ̀ kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá Rẹ̀ Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn Rẹ̀ yóò sì mú-un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn Rẹ̀ Ní ti èmi, mo wí pé Olúwa , ṣàánú fún mí wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ Àwọn ọ̀ta mi ń sọ́rọ̀ mi nínú arankan, pé Nígbà wo ni yóò kú ti orúkọ Rẹ̀ yóò sì run Nígbà kígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí, wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà Rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara Rẹ̀ nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kalẹ̀ Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi èmi ni wọn ń gbìmọ̀ ibi sí, wọ́n wí pé Ohun búburú ni ó di mọ́-ọn sinsin àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí, kì yóò dìde mọ́ Pàápàá ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi, tí gbé gìgíṣẹ̀ Rẹ̀ sókè sí mi Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa , ṣàánú fún mi gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn Èmi mọ̀ pé inú Rẹ̀ dùn sí mi, nítorí ọ̀tá mi kò borí mi Bí ó ṣe tèmi ni ìwọ dì mí mú nínú ìwà òtítọ́ mi ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú Rẹ títí láé Olùbùkún ni Olúwa , Ọlọ́run Ísírẹ́lì láé àti láéláé Àmín àti Àmín Sáàmù 42 Bí àgbọ̀nrín tí ń mí hẹlẹ sí ìpa odò omi, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi n mì hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run Oúnjẹ mi ní omijé mi ní ọ̀sán àti ní òru, nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́, Ọlọ́run Rẹ̀ dà Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí, èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ, èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́ Èéṣe tí o fi n rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi Èéṣe tí ara Rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi Ìwọ ṣe ìrètí ni ti Ọlọ́run, nítorí èmi yóò sáà máa yìn ín Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi nítorí náà, èmi ó rántí Rẹ láti ilẹ̀ Jọ́dánì wá, láti Hámónì láti òkè Mísárì Ibú omi ń pe ibú omi nípa híhó omi ṣíṣàn Rẹ̀ gbogbo rírú omi àti bíbì omi Rẹ̀ bò mí mọ́lẹ̀ Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ Rẹ̀, àti ni àṣálẹ́ ni orin Rẹ̀ wà pẹ̀lú mi àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi Èmi wí fún Ọlọ́run àpátà mi, Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́, nítorí ìnilára ọ̀ta Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀ta mi ń gàn mí, Bí wọn ti ń béèrè ni gbogbo ọjọ́ Níbo ni Ọlọ́run Rẹ wà Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi Èéṣe tí ara Rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi Fi ìrètí Rẹ sínú Ọlọ́run, nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi Sáàmù 43 Dámiláre, Ọlọ́run mi, kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè aláìwà-bí-Ọlọ́run yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀ Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́, nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá Ran ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ Rẹ jáde, jẹ́ kí wọn ó máa dààbò bò mí jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ Rẹ, sí ibi tí ìwọ ń gbé Nígbà náà ní èmi o lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run, sí Ọlọ́run ayọ̀ mí àti ìdùnnú mi, èmi yóò yin ọ pẹ̀lú dùùrù, ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi Fi ìrètí Rẹ sínú Ọlọ́run, nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi Sáàmù 44 Àti fi ètí wa gbọ́, Ọlọ́run àwọn baba wa tí sọ fún wa oun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn, ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn Ìwọ fi ọwọ́ Rẹ̀ lé orílẹ̀-èdè jáde Ìwọ sì gbin àwọn baba wa Ìwọ run àwọn ènìyàn náà Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀ Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọn gba ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kì í se apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò se ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ àti, apá Rẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ojú Rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi, ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jákọ́bù Nípaṣẹ̀ Rẹ̀ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣúbú nípasẹ̀ orúkọ Rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá ti ó dìde sí wa mọ́lẹ̀ Èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá, Ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa, ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́, àwa ó sì yin orúkọ Rẹ̀ títí láé Sela Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde mọ́ Ìwọ ti bá wa jà ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa, àwọn ọ̀ta wa ti gba ilẹ̀ wa, wọ́n sì fi ipá gba oko wa Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárin àwọn aláìkọlà Ìwọ ta àwọn ènìyàn Rẹ fún owó kékeré, Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa, ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́, ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀, nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ojú àwọn ọ̀ta àti olùgbẹ̀san Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa, ṣíbẹ̀ àwa kò gbàgbé Rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mu Rẹ̀ Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà Rẹ̀ Ṣùgbọ́n wọ́n kọ lù wá, ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ajáko tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀ Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí Rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kò inú ọkàn Ṣíbẹ̀, nítorí Rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojojúmọ́ a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa Jí, Olúwa ! Èéṣe tí ìwọ ń sùn Dìde fún ra Rẹ! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú Rẹ mọ́ tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀ Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́ ràwápadà nítorí ìfẹ́ Rẹ tí ó dúró ṣinṣin Sáàmù 45 Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé Gba idà Rẹ mọ́ ìhà Rẹ, ìwọ alágbára jùlọ wọ ara Rẹ̀ ní ògo àti ọla ńlá Nínú ọlá-ńlá Rẹ máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́ jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ ṣe ohun ẹ̀rù Jẹ́ kí ọfà mímú Rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀ Ìjọba Rẹ Ọlọ́run, yóò pẹ́ títí ayé ọ̀pá aládé ni yóò jẹ́ ọ̀pá ìjọba Rẹ Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run Rẹ̀ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀, nípa fífí àmì òróró ayọ̀ kùn ọ́ Gbogbo aṣọ Rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjíá àti alóe àti kaṣíà láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú Rẹ̀ dùn Àwọn ọmọbìnrin àwọn aládé wà nínú àwọn àyànfẹ́ Rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró nínú wúrà ófórì Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí Rẹ̀ sími gbàgbé àwọn ènìyàn Rẹ àti ilé baba Rẹ Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà Rẹ gidigidi nítorí òun ni Olúwa Rẹ kí ìwọ sì máa tẹríba fún un Ọmọbìnrin ọba tirẹ̀ yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojú rere Rẹ̀ Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárin ilé Rẹ̀ aṣọ ìbalẹ̀ Rẹ̀ a ṣe é lọ́sọ̀ọ́ pẹ̀lú wúrà Nínú aṣọ ìbànújẹ́ iyebíye ni a mú-un wá sí ọ̀dọ̀ ọba àwọn wúndíá ẹgbẹ́ Rẹ̀ tẹ̀ lé e wọ́n, sí mú-un tọ̀ ọ́ wá Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn wọ́n sì wọ ààfin ọba Ọmọ Rẹ̀ ni yóò gba ipò baba Rẹ̀ ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo Èmí yóò máa rántí orúkọ Rẹ̀ ní ìran gbogbo nígbà náà ni orílẹ̀ èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé Sáàmù 46 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ nínú ìgbà ìpọ́njú Nítori náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ sí ayé ní ìdí tí òkè sì ṣubú sínú òkun Tí omi Rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára Rẹ̀ Sela Odò ńlá kan wà tí sísàn Rẹ̀ mú ìnú ìlú Ọlọ́run dùn ibi mímọ́, nibi ti ọ̀gá ògo ń gbé Ọlọ́run wà pẹ̀lú Rẹ̀, kò ní yẹ̀ Ọlọ́run yóò ràn an lọ́wọ́ ní kùtùkùtù ọ̀wúrọ̀ Àwọn orílẹ̀ èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba subú ó gbé ohun Rẹ̀ sókè, ayé yọ̀ Ọlọ́run awọn ọmọ ogún wà pẹ̀lú wa Ọlọ́run Jákọ́bù ni ààbò wa Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa irú ahoro tí ó ṣe ní ayé O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná Ẹ dúró jẹ́ẹ kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀ èdè A o gbé mi ga ní ayé Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa Ọlọ́run Jákọ́bù sì ni ààbò wa Sáàmù 47 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀ Báwo ni Olúwa ọ̀gá ògo ti ni ẹ̀rù tó ọba ńlá lórí gbogbo ayé Ó ṣẹ́ àwọn orílẹ̀ èdè lábẹ́ wa àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa ọlá Jákọ́bù, ẹni tí ó fẹ́ wa Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀ Olúwa ti òun ti àriwo ipè Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, Ẹ kọrin ìyìn Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, Ẹ kọrin ìyìn! Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Sáàmù! Ọlọ́run jọba lórí gbogbo ayé Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ Rẹ̀ Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Ábúráhámù nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni òun ni ó ga jùlọ Sáàmù 48 Ẹni ńlá ní Olúwa , tí o sì yẹ láti máa yìn ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ Rẹ̀ Ó dára nínú ipò ìtẹ́ Rẹ̀ ayọ̀ gbogbo ayé òkè Síónì, ní ìhà àríwá ní ìlú ọba ńlá Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin Rẹ̀ ó fi ara Rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀ wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ Wọn ríi bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀ ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Táṣíṣì wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà oorùn Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́ Bẹ́ẹ̀ ni àwa rí, Ní ìnú Olúwa àwọn ọmọ ogun Ní ìlú Ọlọ́run wa Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé Sela Láàrin tẹ́ḿpìlì Rẹ, Ọlọ́run àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ Rẹ Gẹ́gẹ́ bí orúkọ Rẹ Ọlọ́run ìyìn Rẹ̀ dé òpin ayé ọwọ́ ọ̀tún Rẹ kún fún òdodo Jẹ́ kí òkè Síónì kí ó yọ̀ kí inú àwọn ọmọbìnrin Júdà kí ó dùn nítorí ìdájọ́ Rẹ̀ Rìn Síónì kiri lọ yíká Rẹ̀, ka ilé ìsọ́ Rẹ̀ Kíyèsí odi Rẹ̀ kíyèsí àwọn ààfin Rẹ̀ kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀ Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé Sáàmù 49 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn! Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré talákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú! Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ìsọ láti ọkàn mi yóò mú òye wá Èmi yóò yí etí mi sí òwe olókùn ni èmi yóò ṣi ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mí sílẹ̀ lójú okùn dùùrù Èéṣé ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú àti ayan nijẹ yí mi ká, Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọpọlọpọ ọrọ̀ wọn Kò sí ọkùnrin tí o le ra ẹ̀mí ẹnìkejì Rẹ̀ padà tàbí san owó ìràpadà fún Ọlọ́run Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ iyebíye kò sì sí iye owó tó tó fún sísan Rẹ̀ Níti ki ó máa wà títí ayé láì rí ìsà òkú Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú sègbé wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé ibùgbé wọn láti ìrandé ìran wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́ o sì dàbí ẹranko tí o sègbé Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí o gbàgbọ́ nínú ara wọn, àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn, tí o gba ọ̀rọ̀ wọn Sela Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú ikú yóò jẹun lórí wọn ẹni tí ó dúró ṣinṣin ní yóò jọba lórí wọn ní òwúrọ̀ Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́ isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà kúrò nínú isà òkú yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara Rẹ̀ Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnikan bá di ọlọ́rọ̀ Nígbà tí ìyìn ilé Rẹ̀ ń pọ̀ síi nítorí kì yóò mú òun kan dání nígbà tí ó bá kú, ògo Rẹ̀ kòní báa sọ̀kálẹ̀ sí ipò òkú Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara Rẹ̀ Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba Rẹ àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé Sáàmù 5 Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa , kíyèsí àròyé mi Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́, ọba mi àti Ọlọ́run mi, nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí Ní òwúrọ̀, Olúwa , ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi ní òwúrọ̀ èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú Rẹ̀ èmi yóò sì dúró ní ìrètí Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé Àwọn agbéraga kò le è dúró níwájú Rẹ̀ ìwọ kóríra gbogbo àwọn aṣebi Ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn ni Olúwa yóò kórìíra Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú Rẹ̀, èmi yóò wá sínú ilé Rẹ̀ ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba sí ìhà tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ̀ Tọ́ mi, Olúwa , nínú òdodo Rẹ, nítorí àwọn ọ̀ta mi, mú ọ̀nà Rẹ tọ́ níwájú mi Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́ ọkàn wọn kún fún ìparun ọ̀nà ọ̀fun wọn ni iṣà òkú tí ó sí sílẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run! Jẹ́ kí rìkísí wọn jẹ́ ìṣubú wọn Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ Ṣùgbọ́n jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀ jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí Tan ààbò Rẹ sórí wọn, àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ Rẹ yóò máa yọ̀ nínú Rẹ Dájúdájú, Olúwa , ìwọ bùkún olódodo ìwọ fi ojú rere Rẹ yí wọn ká bí àṣà Sáàmù 50 Olúwa , Ọlọ́run Alágbára sọ̀rọ̀ kí o sì pè ayé jọ láti ìlà oorùn títí dé ìwọ̀ Rẹ̀ Láti Síónì wá, pípé ni ẹwà, Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run ń bọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́, iná yóò máa jó níwájú Rẹ̀, àti ní àyíká Rẹ̀ ni ẹ̀fúfù líle yóò ti máa jà ká Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé, kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn Rẹ̀ Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi Àwọn ọ̀run sọ̀rọ̀ òdodo Rẹ̀, Nítorí òun fúnrarẹ̀ ni onídàájọ́ Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Ísírẹ́lì, èmi yóò jẹrìí sí ọ èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run Rẹ Èmi kí yóò bá ọ wí nítorí àwọn ìrúbọ Rẹ̀ tàbí ọrẹ̀ ẹbọ sísun Rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi ní ìgbà gbogbo Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí ó kọ fún un tàbí kí o mú ewúré láti inú agbo ẹran Rẹ̀ Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmí àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá àti gbogbo ẹ̀dá alààyé tí ó wà ní orí ilẹ ni tèmi Bí ebi tílẹ̀ ń pá mí, èmi kì yóò sọ fún ọ, nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo tí ó wa ní inú Rẹ̀ Ǹjẹ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí mú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ Rú ẹbọ ọrẹ sí Ọlọ́run san ẹ̀jẹ̀ Rẹ fún ọ̀gá ògo, Kí o sì pe mí ni ọjọ́ ìpọ́njú, èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn ènìyàn búburú Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mu mi ní ẹnu Rẹ Ìwọ kórìíra àsẹ mi ìwọ sì sá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́-ọn ìwọ sì da ara Rẹ̀ dé àwọn alágbèrè Ìwọ lo ẹnu Rẹ̀ fún aburú ìwọ sì ń fi ahọ́n Rẹ pète ẹ̀tàn Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí ará-kun-rin Rẹ, ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá Rẹ jẹ́ Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́ ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara Rẹ Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run Bí bẹ́ ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹ́pẹ̀rẹ́ láì sí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀ Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ ọpẹ́ bu ọlá fún mi kí ó sì tún ọ̀nà Rẹ̀ ṣe kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án Sáàmù 51 Sàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìdúró sinsin ìfẹ́ Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú Rẹ̀ kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́ Wẹ gbogbo àìṣedédé mi nù kúrò kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi! Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi, nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi Sí ọ, ìwọ nìkan soso, ni mo sẹ̀ sí ni mo sì ṣe búburú níwájú Rẹ̀, kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀ kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọbá ń ṣe ìdájọ́ Ní tòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi Ní tòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀ kọ̀ Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé ísópù, èmi yóò sì mọ́ fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju sínóò lọ Jẹ́ kí ń gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn jẹ́ kí gbogbo egúngún tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀ Pa ojú Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédé mi rẹ́ Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run, kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú Rẹ̀ kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ mi Mú ayọ̀ ìgbàlà Rẹ̀ tọ̀ mí wá kí o sì fún mí ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ àwọn Olùrékọjá ní ọ̀nà Rẹ̀, àwọn ẹlẹ́sẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ Gbàmí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi, ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo Rẹ kíkan Olúwa , sí mi ní ètè mi gbogbo, àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn Rẹ̀ Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọọrẹ̀-ẹbọ sísun Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbínújẹ́ ọkan ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà Ṣe rere ní dídùn inú Rẹ sí Síónì ṣe rere tún odi Jérúsálẹ́mù mọ Nígbà náà ni inú Rẹ yóò dùn sí ẹbọ òdodo, pẹ̀lú ọrẹ-ẹbọ sísun àti ọ̀tọ̀tọ̀ ọrẹ ẹbọ sísun, nígbà náà ni wọn yóò fi akọ màlúù rúbọ lórí pẹpẹ Rẹ̀ Sáàmù 52 Èéṣé tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin Oore Ọlọ́run dúró pẹ́ títí Ahọ́n Rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun ó dà bí abẹ mímú, ìwọ ẹni tí ń hùwà ìrẹ́jẹ Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ire lọ, àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn! Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé, yóò sì dì ọ́ mú, yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó Rẹ yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè Sela Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù wọn yóò sì rẹ́rìn-ín Rẹ̀, wí pé, Èyi ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára Rẹ̀, bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ Rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé ó sì mu ara Rẹ̀ le nínú ìwà búburú Rẹ̀ Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Ólífì tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà láé àti láéláé Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe èmí ní ìrètí nínú orúkọ Rẹ, nítorí orúkọ Rẹ dára Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́ Sáàmù 53 Asiwèrè wí ní ọkàn Rẹ̀ pé Ọlọ́run kò sí Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú kò sì sí ẹnìkan tí ń ṣe rere Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run sórí àwọn ọmọ ènìyàn láti wò bóyá ẹnìkan wà tí ó ní òye, tí ó sì ń wá Ọlọ́run Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà, wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́ kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀ Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun tí wọn kò sì pe Ọlọ́run Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńlá níbì tí ẹ̀rù kò gbé sí nítorí Ọlọ́rún tí fọ́n egungun àwọn tí ó dótì ọ́ ká ìwọ tí dójú tì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn Ìgbàlà Ísírẹ́lì ìbá jáde wá láti Síónì! Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn Rẹ̀ padà, jẹ́ kí Jákọ́bù yọ̀ kí inú Ísírẹ́lì sì máa dùn! Sáàmù 54 Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ Rẹ dá mi láre nípa agbára Rẹ Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi Àwọn àlejò ń dìde sí mí Àwọn aláìláàánú ènìyàn ń wá ayé mi àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn Kíyèsí i Ọlọ́run ni Olùrànlọ́wọ́ mi Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró, pa wọ́n run nínú òtítọ́ Rẹ Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi pa wọ́n run nínú òtítọ́ Rẹ Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ èmi yóò yin orúkọ Rẹ, Olúwa , nítorí tí ó dára Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo ojú mi ti wo ìborí lórí ọ̀ta mi Sáàmù 55 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run, Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́ Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo Sí ohùn àwọn ọ̀ta ni, nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn Ọkàn mi wà nínú ìrọra pẹ̀lú ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi Ìbẹ̀rù àti ìwàrírí wa sí ara mi ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀ Èmi sọ pé, Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà! Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi Èmi ìbá sá lọ jìnnà réré kí ń sì dúró sí ihà Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò, jìnnà kúrò nínú ìjì àti èfúùfù líle Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa , da ahọ́n wọn rú, nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà Ọ̀sán àti oru ní wọ́n fí ń rìn gbogbo odi kiri àrankàn àti èébú wà láàrin Rẹ̀ Ìwà búburú ń bẹ ní àárin Rẹ̀ ìdẹ́rùbà àti irọ́ kò kúrò ní ìgboro Rẹ̀ Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi, èmi yóò fara mọ́ ọn tí ọ̀ta bá gbé ara Rẹ̀ ga sími, èmi ibá sá pamọ́ fún un Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi, ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó sún mọ́ mi, pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádún adùn ìdàpọ̀ bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwujọ ní ilé Ọlọ́run Kí ikú kí ó dé bá wọn, Kí wọn ó lọ láàyè sí isà òkú, Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà, nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run Olúwa yóò sì gbà mí Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán èmi sunkún jáde nínú ìpọ́njú, o sì gbọ́ ohùn mi Ó rà mí padà láìléwu kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi Ọlọ́run yóò gbọ́ yóò sì pọ́n wọn lójú àní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbà a nì— Sela Nítorí tí wọn kò ní àyípadà, tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ Rẹ̀ ó ti bá májẹ̀mú Rẹ̀ jẹ́ Ọ̀rọ̀ ẹnu Rẹ̀ kúnná ju òrí àmọ́, ṣùgbọ́n ogun ija wà ni àyà Rẹ̀ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ, ṣùgbọ́n idà fífà yọ ní wọn Gbé ẹrù Rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa yóò sì mú ọ dúró òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi wá sí ihò ìparun Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ Sáàmù 56 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbọ́nára lépa mi ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà sí mi, wọn ń ni mi lára Àwọn ọ̀ta mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́ àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bàmí, èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ Rẹ nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi ẹ̀rù kì yóò bà mí kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́ wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba Wọn ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi Wọ́n ha le mú un jẹ gbé Ní ìbínú Rẹ, Ọlọ́run, wó àwọn ènìyàn yìí lulẹ̀ Ọlọ́run! Kọ ẹkún mi sílẹ̀ kó omije mi sí ìgò Rẹ wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ Rẹ bí Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́ nípa èyí ní mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ nínú Olúwa , ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi ẹ̀rù kì yóò bà mí kí ni ènìyàn le ṣe sí mi Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ Rẹ Ọlọ́run èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú, kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè Sáàmù 57 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi, nítorí nínú Rẹ ni ààbò ọkàn mí wà Èmi o fi ààbò mí síbi ìyẹ́ apá Rẹ títí tí ewu yóò fi kọjá lọ Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run gíga jùlọ, sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́ fún mi Òun yóò ránsẹ́ láti ọ̀run wá, yóò sì gbà mí bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mì mì tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi Ọlọ́run yóò rán àánú Rẹ̀ àti òdodo Rẹ̀ jáde Mo wà ní àárin àwọn kìnnìún mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú àwọn ènìyàn tí ẹ̀yin wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà ẹni tí ahọ́n Rẹ̀ jẹ́ idà mímú Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ kí ògo Rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ Wọn ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi ṣùgbọ́n wọn ti jìn ṣíbẹ̀ fún ara wọn Ọkàn mi tí múra Ọlọ́run ọkàn mí ti múra, èmi ó kọrin èmi ó si máa kọrin ìyìn Jí, ìwọ ọkàn mi! Jí, ohun orin èlò àti dùùrù! Èmi tìkárami, yóò si jí ní kùtùkùtù Èmi ó máa yín ọ, Olúwa , láàrin àwọn orílẹ̀ èdè èmi ó máa kọrin sí ọ láàrin àwọn ènìyàn Nítorí títóbi ní ìfẹ́ Rẹ, tí ó dé ọ̀run òtítọ́ Rẹ tàn dé àwọ̀sánmọ̀ Gbígbéga ni ọ, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ kí ògo Rẹ̀ kí ó ju gbogbo ayé lọ Sáàmù 58 Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòotọ́ ẹ̀yin ijọ ènìyàn Ǹjẹ́ ẹ̀yìn ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́ ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìsòdodo, Ọmọ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé Ní inú ìyá wọn wá, ni eniyàn búburú tí sìnà lojukan náà tí a ti bí wọn wọn a máa ṣèké Ọ̀rọ̀ wọn dà bí ọ̀rọ̀ ejò, gẹ́gẹ́ bí ti sèbé tí ó dítí Rẹ̀, wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara Rẹ̀ ni etí Tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atinilójú, bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run ní ẹnu wọn ká ọ̀gan àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń ṣàn lọ nígbà tí ó bá fa ọfà Rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́ Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí Rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé bí ọmọ ti oṣu Rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí òòrùn Kí ìkòkò yín kì o tó mọ̀ ìgbóná ẹ̀gún ìbá tutù, ìbá ma jò, yóò fi ìjì gbá wọn lọ Olódodo yóò yọ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú Àwọn ènìyàn yóò wí pé, lóòtọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo lóòtọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé Sáàmù 59 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburú kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ Wòó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí! Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi Kìí se nítorí ìrékọja mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa Èmí kò ṣe àìṣedédé kan, ṣíbẹ̀ wọ́n sáré, wọ́n ṣetán láti kọlù mi Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi Olúwa Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, dìde fún ara Rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀ èdè wí Má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì Sela Wọ́n padà ní àṣálẹ́, wọ́n ń gbó bí àwọn ajá, wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri Kíyèsí ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn, wọn sì wí pé, Ta ní ó le gbọ́ ọ̀rọ̀ wa Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa , yóò fi wọ́n rẹ́rin-ín Ìwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi, Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi Yóò sì jẹ́ kí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gún lórí àwọn ọ̀tá ìfẹ́ àwọn ọ̀ta mi Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa, kí àwọn ènìyàn mí má ba à gbàgbé Nínú agbára Rẹ̀, jẹ́ kí wọ́n máa rìn kiri, kí ó sì Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn, ni ọ̀rọ̀ ètè wọn, kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn Nítorí ẹ̀gàn àti èké tí wọn ń sọ, Pa wọn run nínú ìbínú, run wọ́n di ìgbà tí wọ́n kò ní sí mọ́ Nígbà náà ní yóò di mímọ̀ dé òpin ayé pé Ọlọ́run jọba lórí Jákọ́bù Sela Wọ́n padà ní àsálẹ́, wọn ń gbó bí àwọn ajá wọ́n ń rìn ìlú náà káàkiri Wọ́n ń rín kiri fún oúnjẹ wọn sì ń yán nígbà tí wọn kò yó Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára Rẹ, ń ó kọrin ìfẹ́ Rẹ ní òwúrọ̀ nítorí ìwọ ni ààbò mi, ibi ìsádì mi ní ìgbà ìpọ́njú Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi Sáàmù 6 Olúwa , Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú Rẹ kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú Rẹ Ṣàánú fún mi, Olúwa , nítorí èmi ń ku lọ Olúwa , wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira Ọkàn mi wà nínú ìrora Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa , yóò ti pẹ́ tó Yípadà, Olúwa , kí ó sì gbà mí gbà mí là nípa ìfẹ́ Rẹ tí kì í ṣákìí Ẹnikẹ́ni kò sì rántí Rẹ nígbà tí ó bá kú Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú iṣà òkú Agara ìkérora mi da mi tán gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́ wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú Olúwa ti gba àdúrà mi Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀ Sáàmù 60 Ìwọ tí kọ̀ wá sílẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká ìwọ ti bínú nísìnsín yìí, tún ara Rẹ yípadà sí wá Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ mú fífọ́ Rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mi Ìwọ ti fi ìgbà ewu hàn àwọn ènìyàn Rẹ Ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wa gbọ́n-ọ́ngbọ́n-ọ́n Àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ ní ìwọ fi ọ̀págun fún kí a lè fíhàn nítorí òtítọ́ Sela Fi ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ gbà wá kí ó sì ràn wá lọ́wọ́, kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ Rẹ̀ Ní ayọ̀, èmi ó pín ṣèkémù jáde èmi o sì wọ̀n àfonífojì ṣúkótù Tèmi ni Gílíádì, tèmi sì ni Mánásè Éfúráímù ni àsìbórì mi, Júdà sì ní ọ̀pá àṣẹ mi Móábù ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Édómù ní mo bọ́ bàtà mi sí lórí fìlísitinì ni mo kígbe ayọ̀ Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Édómù Kí ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀ tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́ Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá, nítorí asán ní ìrànlọ́wọ́ ènìyàn Nípa Ọlọ́run ni a ó ní ìṣẹ́gun, yóò sì tẹ̀ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀ Sáàmù 61 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run Tẹ́tí sí àdúrà mi Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́, mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀ mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi, ilé ìsọ́ agbára àwọn ọ̀tá Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ Rẹ títí láé kí ń sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá Rẹ Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ Rẹ̀ Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí o gùn, ọdùn Rẹ̀ fún ìrandíran Kí o máa jọba níwájú Ọlọ́run títí láé pèsè àánú àti òtítọ́ Rẹ̀ tí yóò máa ṣe ìtọ́ju Rẹ Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ títí láé kí ń san ẹ̀jẹ́ mí ní ojoojúmọ́ Sáàmù 62 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ wá Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi oun ní ààbò mi, a kí yóò sí mi ní pò padà Ẹ̀yin ó ti máa rọ́lù ènìyàn kan pẹ́ tó Gbogbo yín ni ó fẹ pa á, bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀ àti bí ọgbà tí ń wó lọ Kìkì èró wọn ni láti bì ṣubú kúrò nínú ọlá Rẹ̀ inú wọn dùn sí irọ́ Wọn ń fi ẹnu wọn súre, ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn nínú ọkàn wọn Sela Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmí wà, ìwọ Ọlọ́run mi Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi Òun ni ààbò mi, a kí yóò sí mi nípò Ìgbàlà mi àti ògo mí dúró nínú Ọlọ́run Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn tú ọkàn Rẹ̀ jáde sí i, nítorí Ọlọ́run ní ààbò wa Ní tòótọ́, asán ní àwọn ọmọ ènìyàn, èké si ni àwọn olóyè, wọn gòkè nínú ìwọ̀n bákan náà ni wọn fẹ́rẹ̀ jù asán lọ lápapọ̀ wọn jẹ èémí Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnílára, tàbí gbéraga nínú olè jíjà, nítòótọ́ bí ọrọ̀ Rẹ̀ ń pọ̀ síi, má ṣe gbẹ́kẹ̀ Rẹ̀ lé wọn Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo gbọ́ èyí pé, ti Ọlọ́run ní agbára Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa , tirẹ ni àánú nitorí ti iwọ san án fun olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ Rẹ̀ Sáàmù 63 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, nígbà gbogbo ní mo ń ṣàfẹ́rí Rẹ óùngbẹ́ Rẹ ń gbẹ ọkàn mi ara mi fà sí ọ, ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ ti ń ṣàárẹ̀ níbi tí kò sí omi Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́ mo rí agbára àti ògo Rẹ Nítorí ìfẹ́ Rẹ dára ju ayé lọ, ètè mi yóò fògo fún ọ Èmi o yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ Rẹ A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ Nígbà tí mo rántí Rẹ lórí ìbusùn mi èmi ń ronú Rẹ títí iṣọ́ òru Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi, mo kọrin níbi òjijì-ìyẹ́ apá Rẹ Ọkàn mí fà sí ọ ọwọ́ ọ̀tún Rẹ gbé mi ró Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ní a ó parun wọn o sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìṣàlẹ̀ ilẹ̀ ayé Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run ẹni tí o fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò sògo ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pa mọ́ Sáàmù 64 Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Wọn pọ́n ahọ́n wọn bí idà wọn sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò Wọ́n tafà ní kọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀ wọ́n tafà sí lojijì, wọn kò sì bẹ̀rù Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú, wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹ́kun sílẹ̀ ní kọ̀kọ̀ wọ́n wí pé, Ta ni yóò rí wa Wọ́n gbìmọ̀ àìsòdodo, wọn wí pé, A wa ti parí èrò tí a gbà tán lóòtọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n Gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe Jẹ́ kí Olódodo kí o yọ̀ nínú Olúwa yóò sì rí ààbò nínú Rẹ̀ Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ni àyà yóò máa yìn ín Sáàmù 65 Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ni Síónì sì ọ ni a o mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ Ìwọ tí o ń gbọ́ àdúrà, gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ Rẹ Ọ̀ràn àìṣedédé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni! Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ Rẹ! A tẹ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé Rẹ, ti tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohùn ìyanu ti òdodo, Ọlọ́run olùgbàlà wa, ìrètí gbogbo òpin ayé àti àwọn tí ó jìnnà nínú òkun, Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára Rẹ tí ó di ara Rẹ̀ ní àmùrè agbára Ẹni tí ó mú ríru omi òkun dákẹ́ ríru ariwo omi wọn, àti gìdìgìdì àwọn ènìyàn Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù agbára Rẹ̀ ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ̀ yọ ìwọ pé orin ayọ̀ jáde Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin ìwọ mú ní ọ̀rọ̀ púpọ̀ Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kún fún omi láti pèsè ọkàn fún àwọn ènìyàn, nítorí ibẹ̀ ní ìwọ ti yàn án Ìwọ fi ìrinmi sí aporo Rẹ ìwọ tẹ́ ògúlùtù Rẹ ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ Rẹ rọ̀ o sì bùkún ọ̀gbìn Rẹ Iwọ fi oore Rẹ de ọdún ni adé, ọ̀rá ń kan ni ipa-ọ̀nà Rẹ Pápá-tútù ni ihà ń kán àwọn òkè kékèké fi ayọ̀ di ara wọn ni àmùrè Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà, ni asọ àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀, wọn hó fún ayọ̀, wọn ń kọrin pẹ̀lú Sáàmù 66 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, gbogbo ayé! Ẹ kọrin ọ̀lá orúkọ Rẹ̀ Ẹ fún un ní ìyìn, ògo, Ẹ wí fún Ọlọ́run pé, ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ Rẹ̀! Nípa ọ̀pọ̀ agbára Rẹ ni àwọn ọ̀tá Rẹ yóò fi sìn ọ́ Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ wọn ń kọrin ìyìn sí ọ, wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ Sela Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe, Iṣẹ́ Rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn! O yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ, wọ́n fi ẹsẹ̀ rìn inú omi kọjá, níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú Rẹ O ń jọba títí láé nípa agbára Rẹ̀, ojú Rẹ̀ ń wò orílẹ̀ èdè kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga Sela Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn, jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohun ìyìn Rẹ̀ O ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí o yẹ̀ Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, Dan wa wò ìwọ dán wa bí a tí ń Dan fàdákà wo Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n o sì di ẹ̀rù lé ẹ̀yìn wa Ìwọ mú àwọn ènìyàn gun wá ní orí àwa la iná àti omi kọjá ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀ Èmi ó wá sí tẹ́ḿpìlì Rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ Ẹ̀jẹ́ ti ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ nígbà tí mo wà nínú ìsòro Èmi o sun ẹbọ ọlọ́ràá sí ọ àti ẹbọ ọ̀rá àgbò èmi o rú akọ màlúù àti ewúrẹ́ Sela Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i Ìyìn Rẹ̀ wà ní ẹnu mi Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi, Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́ o ti gbọ́ ohun mi nínú àdúrà Ìyìn ni fún Ọlọ́run ẹni tí kò kọ àdúrà mi tàbí mú ìfẹ́ Rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi! Sáàmù 67 Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí o sì bùkún fún wa kí ó sì jẹ́ kí ojú Rẹ̀ tàn yí wa ká, kí ọ̀nà Rẹ̀ le di mímọ̀ ní ayé, ìgbàlà Rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run kí gbogbo ènìyàn kí o yìn ọ! Kí orílẹ̀ èdè kí o yọ̀, kí o sì kọrin fún ayọ̀, nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn ìwọ si jọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́ Sela Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè Rẹ̀ wá, Ọlọ́run, Ọlọ́run wa yóò bùkún fún wa Ọlọ́run yóò bùkún fún wa, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù Rẹ̀ Sáàmù 68 Kí Ọlọ́run kí o dìde, kí àwọn ọ̀ta Rẹ̀ kí ó fọ́nká kí àwọn ọ̀ta Rẹ̀ kí ó sá níwájú Rẹ̀ Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ, kí ó fẹ́ wọn lọ bí ìdà tí i yọ́ níwájú iná, kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀ Ẹ kọrin sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn síi, ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń ré kọjá ní ihà JAH ni orúkọ Rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Rẹ̀ Baba àwọn aláìní baba àti Onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ni ibùgbé Rẹ̀ mímọ́ Ọlọ́run gbé ẹni òfo kálẹ̀ nínú ìdílé, ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn Rẹ̀, Ọlọ́run, tí ń kọjá lọ láàrin ihà, Sela Ilẹ̀ mi títí, àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde, níwájú Ọlọ́run, ẹni Sínáì, níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run ìwọ tu ilé inú Rẹ̀ lára nígbà tí ó Rẹ̀ ẹ́ tan Àwọn ènìyàn Rẹ tẹ̀dó ṣíbẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní Rẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀, púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí o ń ròyìn Rẹ Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ Obìnrín tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà Nígbà tí ẹ̀yin sùn láàrin àwọn àgọ́ iná, nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí apá àdàbà ti a bò ní sílífa Nígbà ti Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà, ó dàbí òjò dídi ní Salímónì Òkè Básánì jẹ́ òkè Ọlọ́run òkè tí ó ní orí púpọ̀ ní òkè Básánì Kí ló dé ti ẹ̀yin fi ń lára, ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jọba níbi tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò máa gbé títí láé Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún Olúwa ń bẹ láàrin wọn ní Sínáì ni ibi mímọ́ Rẹ̀ Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbékùn lọ ìwọ ti gbà ẹ̀bùn fún ènìyàn nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú, Kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé Olùbùkún ni Ọlọ́run, sí Ọlọ́run Olùgbàlà wa, ẹni tí ó ń fi ojojúmọ́ gba ẹrù wa rù Sela Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà àti sí Olúwa Ọlọ́run ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá Rẹ̀, àti agbárí onirun àwọn tó ń tẹ̀ṣíwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn Olúwa wí pé, Èmi o mú wọn wá láti Báṣánì èmi ó mú wọn wá láti ibú omi òkun, Kí ẹṣẹ̀ Rẹ̀ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá Rẹ̀, àti ahọ́n àwọn ajá Rẹ̀ ní ìpín ti wọn lára àwọn ọ̀tá Rẹ Wọn ti rì ìrìn Rẹ, Ọlọ́run, irin Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ Rẹ̀ Àwọn akọrin ní íwájú, tí wọn ń lu tanborí Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́ àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Ísírẹ́lì wá Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Bẹ́ńjámínì wà, tí o ń darí wọn, níbẹ̀ ni àwọn ọmọ aládé Júdà, níbẹ̀ ni àwọn ọmọ aládé Sébúlúnì àti tí Náfútàlì Pàsẹ agbára Rẹ, Ọlọ́run fi agbára Rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tẹ́lẹ̀ Nítorí tẹ́ḿpìlì Rẹ ni Jérúsálẹ́mù àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ Bá àwọn ẹranko búburú wí, tí ń gbé láàrin ìko ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù títí olúkúlùkù yóò fi forí balẹ̀ pẹ̀lú ìwọn fàdákà tú àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe inú dídùn si ogun ká Àwọn ọmọ aládé yóò wá láti Éjíbítì Jẹ́ kí Etiópíà na ọwọ́ Rẹ̀ sí Ọlọ́run Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé, kọrin ìyìn sí Olúwa , Sela Sí ẹni tí ń gún ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè, tó ń fọhùn Rẹ̀, ohùn ńlá Kéde agbára Ọlọ́run, ọlá ńlá Rẹ̀ wà lórí Ísírẹ́lì tí agbára Rẹ̀ wà lójú ọ̀run Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ Rẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi agbára àti òkun fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ Olùbùkún ní Ọlọ́run! Sáàmù 69 Gbàmí, Ọlọ́run, nítorí omi tí kún dé ọrùn mi Mo ń rì nínú ìrà jínjìn, níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé Mo ti wá sínú omi jínjìn ìkún omi bò mí mólẹ̀ Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́ ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú, nígbà ti èmi dúró de Ọlọ́run mi Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí wọn ju irun orí mi lọ púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí, àwọn tí ń wá láti pa mí run A fi ipá mú mi láti san ohun tí èmi kò jí Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú Rẹ Má ṣe dójú tì àwọn tí ó ní ìrètí nínú Rẹ nítorí mi, Olúwa , Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi, Ọlọ́run Ísírẹ́lì Nítorí Rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn, ìtìjú sì bo ojú mi Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi Nítorí ìtarà ilé Rẹ jẹ mí run, àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí Nígbà tí mo sunkún tí mo sì ń fi ààwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù Nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà, àwọn ènìyàn ń pòwe mọ́ mi Àwọn tí ó jòkòó ní ẹnu ibodè ń bú mi, mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni ìwọ ni èmi n gbàdúrà mi sí Olúwa , ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi Rẹ, dá mí lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà Rẹ tí ó dájú Gbá mí kúrò nínú ẹrẹ̀, Má ṣe jẹ́ kí ń rí gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí o korìíra mi, kúrò nínú ibú omi Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu Rẹ̀ dé mọ́ mi Dá mí lóhùn, Olúwa nínú ìṣeun ìfẹ́ Rẹ nínú ọ̀pọ̀ àánú Rẹ yípadà sí mi Má ṣe pa ojú Rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú Súnmọ́ tòsí kí ó sì gbà mí là rà mí padà nítorí àwọn ọ̀ta mi Ìwọ tí mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá Gbogbo àwọn ọ̀ta mi wà níwájú Rẹ̀ Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́ wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́ Mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí, mo ń wá olùtùnú, Ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi, àti ní òungbẹ mi, wọn fi ọtí kíkan fún mi Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó dí ìkẹ́kùn ni iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ fún àwọn tó wà ní àlàáfíà Kí ojú wọn kií ó ṣókùnkùn kí wọ́n má ṣe ríran, kí eyín wọn di títẹ̀ títí láé Tú ìbínú Rẹ jáde sí wọn kí ìbínú gbígbóná Rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀ Kí ibùjókòó wọn di ahoro kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù, àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà Rẹ Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè kí á má kà wọn pẹ̀lú àwọn olódodo Ṣùgbọ́n talákà àti ẹni-ìkáánú ni èmí, Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà Rẹ gbé mi lékè Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga èmi yóò fí ọpẹ́ gbé orúkọ Rẹ̀ ga Eléyìí tẹ Ọlọ́run lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo Rẹ̀ àti bàtà Rẹ̀ Àwọn òtòsì yóò rí wọn yóò sì yọ̀ Ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yin yóò sì wà láàyè! Olúwa , gbọ́ ti aláìní kí o sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀ Kí ọ̀run àti ayé yìn ín, òkun àti àwọn tí ń gbé inú Rẹ̀, Nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Síónì là yóò sì tún àwọn ìlú Júdà wọ̀nyí kọ́ Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀, kí wọn ó lè máa níi ni ilẹ̀ ìní Àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún Rẹ̀, àwọn ti ó fẹ́ orúkọ Rẹ ní yóò máa gbé inú Rẹ̀ Sáàmù 7 Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú Rẹ gba mí là kí o sì tú mí sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi, kí wọn ó má bá à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún wọn a ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gba mí Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi tí mo ja ọ̀ta mí lólè láìnídìí Nígbà náà jẹ́ kí ọ̀ta mi le mi kí wọn sì mú mi jẹ́ kí òun kí ó tẹ ẹ̀mí mi mọ́lẹ̀ kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku Sela Dìde, Olúwa , nínú ìbínú Rẹ dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀ta mi Jí, Ọlọ́run mi kéde òdodo Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yí ká Jọba lórí wọn láti òkè wá Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa , gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ Ọlọ́run Olódodo, Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn, tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́ Aṣà mi ní Ọlọ́run tí ó gajù, ẹni tí ń dáàbò bo àwọn ẹni gíga nípa ti èmi Ọlọ́run ni onídàájọ́ tòótọ́, Ọlọ́run tí ń sọ ìrúnú Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ Bí kò bá yípadà, òun yóò pọ́n idà Rẹ̀ mú ó ti fa ọrun Rẹ̀ le ná ó ti múra Rẹ̀ sílẹ̀ Ó ti pèṣè ohun ìjà ikú sílẹ̀ ó ti pèṣè ọfà iná sílẹ̀ Ẹni tí ó lóyún ohun búburú, tí ó sì lóyùn wàhálà ó bí èké jáde Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde jìn sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀ Wàhálà tí ó fà padà sórí Rẹ̀ Ìwà ipá Rẹ̀ padà sórí ara Rẹ̀ Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo Rẹ̀ Èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa tí ó ga jùlọ Sáàmù 70 Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là, Olúwa , wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́ Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi kí a dojú tì wọ́n, kí wọn sì dààmú kí àwọn tó ń wá ìparun mi yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè ìtìjú àwọn tí ń wí pé, Áà! Áà! Ṣùgbọ́n kí àwọn tí o ń wà ọ ó máa yọ̀ kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa Rẹ, kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà Rẹ máa wí pé, Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga! Ṣíbẹ̀ mo jẹ́ òtòsì, mo sì jẹ́ aláìní wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùtúsílẹ̀ mi Olúwa , má ṣe dúró pẹ́ Sáàmù 71 Nínú Rẹ̀, Olúwa , ní mo ní ààbò Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí Gbà mí kí ó sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo Rẹ kọ etí Rẹ sími kí o sì gbà mí Jẹ́ àpáta ààbò mi, nibi tí èmi lè máa lọ pa àṣẹ láti gbà mí, nítorí ìwọ ni àpáta àti asà mi Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú, ní ọwọ́ aláìsòdodo àti ìkà ọkùnrin Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Ọlọ́run, ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mí láti ìgbà èwe Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi Ìwọ mu mi jáde láti inú ìyá mi wá èmi ó máa yìn ọ títí láé Mo di ẹni ìyanu fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára Ìyìn Rẹ̀ kún ẹnu mi, o ń sọ ti ọlá Rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo Má ṣe ta mí nù ni ọjọ́ ogbó mi Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́ Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ òdì sí mi àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀ Wọ́n wí pé, Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lépa Rẹ̀ kí ẹ sì mu nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti rànmí lọ́wọ́ Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù bò àwọn tí ń wá ìpalára mi Ṣùgbọ́n ní tèmí, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sì i Ẹnu mí yóò sọ nípa ti òdodo Rẹ, ti ìgbàlà Rẹ ni gbogbo ọjọ́ lóòtọ́, èmi kò mọ́ iye Rẹ̀ Èmi ó wá láti wá kéde agbára Olúwa Ọlọ́run èmi ó kéde òdodo Rẹ̀ nìkan Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ tí kọ́ mí títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí ẹnu di arúgbó tán tí mo sì hewú, Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run títí tí èmi o fi ipá re han ìran yìí àti agbára Rẹ fún gbogbo àwọn ará ẹ̀yìn, sọ ti agbára sí ìran tí ń bọ̀ agbára Rẹ̀ fún àwọn tí yóò wá Ọlọ́run, Òdodo Rẹ̀ dé ọ̀run, ìwọ tí ó ti ṣe ohun ńlá Ta ni, Ọlọ́run, tí o dà bí i Rẹ Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí o pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀ Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi ìwọ yóò tù mí nínú ní hà gbogbo Èmi yóò fi dùùrù mi yìn fún òtítọ́ Rẹ, Ọlọ́run mi èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù ìwọ ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn nígbà tí mo bá kọrín ìyìn sí ọ èmi, ẹni tí o ràpadà Ahọ́n mí yóò sọ ti òdodo Rẹ ní gbogbo ọjọ́, fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi Sáàmù 72 Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run, ọmọ aládé ni ìwọ fi òdodo Rẹ fún Yóò ṣe ìdàjọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀ pẹ̀lú òdodo yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn talákà Rẹ Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn àti òkè kékèké nípa òdodo Yóò dábò bò àwọn tí a pọ́n lójú láàrin àwọn ènìyàn yóò gba àwọn ọmọ aláìní yóò sì fa àwọn aninilára ya Àwọn òtòsì àti aláìní yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn, yóò ti pẹ́ tó, láti ìran díran Yóò dàbí òjò tí o ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀ Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀ Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ Rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà títí tí oṣùpá kò fi ní sí mọ́ Yóò máa jọba láti òkun dé òkun àti láti odò títí dé òpin ayé Àwọn tí ó wà ní ihà yóò tẹríba fún un àwọn ọ̀ta Rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀ Àwọn ọba Táṣíṣì àti tí erékùṣù wọn yóò mú ọrẹ wá fún un àwọn ọba Ṣéba àti Síbà wọn o mú ẹ̀bùn wá fún-un Gbogbo ọba yóò tẹríba fún-un àti gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sìn ín Nítorí yóò gba àwọn aláìní nígbà tí ó bá ń ké, tálákà àti ẹní tí kò ni olùrànlọ́wọ́ Yóò káànú àwọn aláìlera àti aláìní yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú Rẹ Yóò sì yè pẹ́! A ó sì fún un ní wúrà Ṣébà Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún-un nígbà gbogbo kí a sì bùkún fún-un lójojúmọ́ Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀ ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà kí èso Rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lébánónì yóò máa gbá yìn-ìn bí koríko ilẹ̀ Kí orúkọ Rẹ̀ kí o wà títí láé orúkọ Rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọn bí òòrùn yóò ti pẹ́ tó wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nipaṣẹ̀ Rẹ Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún Olùbùkún ní Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́li, ẹnìkan ṣoṣo tí ó n ṣe ohun ìyanu Olùbùkun ni orúkọ Rẹ tí ó lógo títí láé kí gbogbo ayé kún fún ògo Rẹ Àmín àti Àmín Èyí ni ìpàrí àdúrà Dáfídì ọmọ Jéṣè Sáàmù 73 Nítòótọ̀ Ọlọ́run dára fún Ísírẹ́lì, fún àwọn ọlọ́kàn funfun Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣeféfé nígbà tí mo bá rí ọlá àwọn ènìyàn búburú Wọn kò ṣe wàhálà ara wọn mókun wọn sì lágbára Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ si ènìyàn a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlomíràn Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn ìwà ìpá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìsòdodo ti wá ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdiwọ̀n Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀ òdì níti ìnilára, wọn ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run ahọ́n wọn gba ipò ayé Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ Wọ́n wí pé, Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀ Ọ̀gá ògo ha ní ìmọ̀ bí Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí ènìyàn asán, wọn ń pọ̀ ní ọrọ̀ Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́ nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́sẹ̀ Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu a sì ń jẹ mí níyà ní gbogbo òwúrọ̀ Bí mo bá wí pé, Èmi ó wí báyìí, Èmi ó ṣẹ̀sí ìran àwọn ọmọ Rẹ̀ Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, O jẹ́ ìnilára fún mi Tí tí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi, Lótítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan! Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọn pátapáta! Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí, bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa , ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn Nígbà tí inú mi bàjẹ́ àti ọkàn mi sì korò, Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye mo jẹ́ ẹranko ní ìwájú Rẹ Ṣíbẹ̀ mo wà pẹ̀lú Rẹ nígbà gbogbo ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú Ìwọ fi ìmọ̀ràn Rẹ tọ́ mi ní kẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn Rẹ Ara mi àti ọkàn mi leè kùnà ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi àti ìpín mi títí láé Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé ìwọ ti pa gbogbo wọn run tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ Rẹ Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run Èmi ti fi Olúwa Ọlọ́run ṣe ààbò mi Kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ Rẹ Sáàmù 74 Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé Èéṣe tí ìbínú Rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá Rẹ Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́, ẹ̀yà ilẹ̀ ìní Rẹ, tí ìwọ ti ràpadà Òkè Síónì, níbi tí ìwọ ń gbé Yí ẹṣẹ̀ Rẹ̀ padà sí ìparun ayérayé wọn, gbogbo ìparun yìí tí ọ̀ta ti mú wá sí ibi mímọ́ Àwọn ọ̀tá Rẹ ń bú ramú-ramù láàrin ìja ènìyàn Rẹ, wọ́n ń gbé Àṣìá wọn sókè fún àmì Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké Rẹ̀ sókè láti gé igi igbó dídí Ṣùgbọ́n nìsìnsìn yìí iṣẹ́ ọnà fínfín ní wọn fi àáké òòlù wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà Wọ́n sun ibi mímọ́ Rẹ̀ lulẹ̀ wọ́n ba ibùgbé orúkọ Rẹ̀ jẹ́ Wọ́n wí ní ọkàn wọn Àwa ó run wọ́n pátapáta! Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan kò sí wòlíì kankan ẹnìkan kan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà Àwọn ọ̀ta yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run Àwọn ọ̀ta yóò ha ba orúkọ Rẹ jẹ́ títí láé Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ Rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún Rẹ Mú-un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ Rẹ kí o sì run wọ́n! Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́ ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé Ìwọ ni ó la òkun sílẹ̀ nípa agbára Rẹ Ìwọ fọ́ orí àwọn abàmì ẹ̀dá nínú omi Ìwọ fọ́ orí Lefiatani túútúú, o sì fi se oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá ti ń gbé inú ìjù Tìrẹ ní ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú ìwọ fi ìdí òòrùn àti òṣùpá lélẹ̀ Iwọ ya orísun omi àti iṣàn omi Ìwọ mú kí odò tó ń ṣàn gbẹ Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú ìwọ yà oòrùn àti òsùpá Ìwọ pààlà etí ayé Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn Rẹ, Olúwa bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ Rẹ jẹ́ Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà Rẹ fún ẹranko ìgbẹ́ búburú Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn Rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé Bojúwo májẹ̀mu Rẹ, nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú jẹ́ kí àwọn aláìní àti talákà yin orúkọ Rẹ Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara Rẹ̀ rò rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn Rẹ ní gbogbo ọjọ́ Má ṣe gbàgbé ohun àwọn ọ̀tá Rẹ, bíbú àwọn ọ̀tá Rẹ, tí ó ń pọ̀ síi nígbà gbogbo Sáàmù 75 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run, a yìn ọ́, nítorí orúkọ Rẹ̀ súnmọ́ tòsí àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu Rẹ Ìwọ wí pé, Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀ Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì, Èmi ni mo di òpó Rẹ̀ mú ṣinṣin Èmí wí fún àwọn agbéraga pé Ẹ má ṣe gbéraga mọ́ àti sí ènìyàn búburú Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè Ẹ máa ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle Nítorí ìgbẹ́kẹ̀lé kò ti ìlà-oòrùn wá tàbí ní ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúsù wá Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdajọ́ Òun Rẹ̀ ẹnìkan sílẹ̀, ó sí ń gbé ẹlòmíràn ga Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà, ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pòpọ̀ mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde, àti búburú ayé gbogbo mú u sílẹ̀ pátapáta Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn Rẹ títí láé Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jákọ́bù Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú, Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga Sáàmù 76 Ní Júdà ni a mọ Ọlọ́run orúkọ Rẹ̀ sì lágbára ní Ísírẹ́lì Àgọ́ Rẹ̀ wà ní Sálẹ́mù, ibùgbé Rẹ̀ ní Síónì Níbẹ̀ ní o ṣẹ́ ọfà, asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun Sela Iwọ ni ògo àti ọlá Ju òkè-ńlá íkogun wọ̀nyìí lọ Àwọn akíkanjú ọkùnrin A kó àwọn akíkanjú ogun ní ìkógun wọn sún oorun ìgbẹ̀yìn wọn kò sí ọ̀kan nínú àwọn ajagun tó lè gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè Ní ìfìbú Rẹ, Ọlọ́run Jákọ́bù, àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dúbúlẹ̀ ṣíbẹ̀ Ìwọ nìkan ni o yẹ kí a bẹ̀rù Ta ló lé dúró níwájú Rẹ nígbà tí ìwọ bá ń bínú Ìwọ ń ṣe ìdàjọ́ láti ọ̀run, ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ ẹ́ Nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run, bá dìde láti ṣe ìdájọ́, láti gba àwọn ẹni ìnílára ilẹ̀ náà Sela Lóòtọ́, ìbínú Rẹ̀ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ, ẹni tí ó yọ nínú ìbínú Rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara Rẹ ni àmùrè Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run Rẹ kí o sì mú-un ṣẹ kí gbogbo àwọn tí ó yíi ká mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí o tọ́ láti bẹ̀rù Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò àwọn ọba ayé sì n bẹ̀rù Rẹ̀ Sáàmù 77 Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú, mo wá Olúwa ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ ọkàn mí sì kọ láti tùú nínú Èmi rántí i Rẹ, Ọlọ́run, mo sì kẹ́dùn mo ṣe àroyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì Sela Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fí ojú ba òorùn, mo dàámú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀ Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì ọdún pípẹ́ sẹ́yìn Mo rántí orin mi ní òru Èmi ń bá àyà mí sọ̀rọ̀, ọkàn mí sì ń ṣe àwárí jọjọ Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé Kí yóò ha ṣe ojú rere Rẹ̀ mọ́ Ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ àti àánú Rẹ̀ tí kú lọ láéláé Ìlérí Rẹ̀ ha kùnà títí ayé Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú Ní ìbínú Rẹ̀, ó ha sé ojú rere Rẹ̀ mọ́ Sela Èmí wí pé, Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi, pé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́ Èmi ṣàṣárò lórí iṣẹ́ Rẹ gbogbo pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára Rẹ Ọlọ́run, Ọ̀nà Rẹ jẹ́ mímọ́ Ọlọ́run wo ní ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu ìwọ fi agbára Rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn Pẹ̀lú ọwọ́ agbára Rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà, àwọn ọmọ Jákọ́bù àti Jósẹ́fù Sela Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run, nígbà tí àwọn omi rí ọ, ẹ̀rù bà wọ́n, nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀ Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀, àwọ̀sánmọ̀ fí àrá dáhùn ọfà Rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú Àrá Rẹ̀ ni a gbọ ní ibi ìjì, ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì Ìpa Rẹ̀ gba òkun, ọ̀nà Rẹ ń bẹ nínú òkun, Ọ̀nà la omi alágbára kọ́já ipa Rẹ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá, nítòótọ́ a kò rí ojú ẹṣẹ̀ Rẹ̀ Ó tọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nípa ọwọ́ Mósè àti Árónì Sáàmù 78 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi tẹ́tí Rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi Èmi ó la ẹnu mi ní òwe èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́ Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀, ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa Àwa kí yóò pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ, ní fífí ìyìn Olúwa , àti ipa Rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn fún ìran tí ń bọ̀ Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jákọ́bù o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Ísírẹ́lì, èyí tí ó páláṣẹ fún àwọn baba ńlá wa láti kọ́ àwọn ọmọ wọn, Nítorí náà àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí i bí tí yóò dìde ti wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn Nígbà náà ni wọn o fi ìgbẹ̀kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run ṣùgbọ́n wọn o pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́ Wọn ò ní dàbí àwọn baba ńlá wọn ìran aláyà líle àti ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn wọn kò sòòtọ̀ si oloore Àwọn ọkùnrin Éfúráímù, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun, wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun Wọ́n kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́ wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin Rẹ̀ Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe, àwọn ìyanu tí ó ti fi hàn wọ́n O ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Éjíbítì, ní agbégbé Síónì O pín òkun níyà, ó sì mú wọn kọjá ó mù kí ó nà dúró bá ebè Ní ọ̀ṣán ó fi ìkúùku àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn àti ní gbogbo òru pẹ̀lú, ìmọ̀lẹ̀ ìná Ó sán àpáta ní ihà ó si fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ẹni pé láti inú ibú wá O mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta omi sìṣsàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò Wọ́n sì tún tẹ̀ṣíwájú láti dẹ́sẹ̀ sí i ní ìsọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá ògo ní àgìnjú Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún Wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, wí pé Ọlọ́run ha lè tẹ tábìlì ní aṣálẹ̀ Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde, odò sì ṣàn lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ ó ha le pèṣè ẹran fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi iná Rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jákọ́bù, ìbínú Rẹ̀ sì rú sí Ísírẹ́lì, Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́ wọn kò sí gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà Rẹ̀ Ṣíbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run ó sì sí ilẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀ Ó rọ mánà fún àwọn ènìyàn láti jẹ, ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn ańgẹ́lì o fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó Ó sṣ́ afẹ́fẹ́ ìlà òòrùn láti ọ̀run wá ó mú afẹ́fẹ́ gúsù wá nípa agbára Rẹ̀ Ó rọ ọ̀jọ̀ ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀, àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìyànrìn etí òkun Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn, yíká àgọ́ wọn Wọn jẹ, wọ́n sí yó jọjọ nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọ́n fìtara bẹ̀bẹ̀ fún, nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn, Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn, ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Ísírẹ́lì bolẹ̀ Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọn ń sá síwájú nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́ O fi òpin sí ayé wọn nínú asán àti ọdún wọn nínú ìpayà Nígbà kígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n, wọn yóò wá a kirì wọn yóò fi ìtara yípadà sí i Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn wí pé Ọlọ́run ọ̀gá ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n-ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n wọ́n fí ahọ́n wọ́n purọ́ fún un Ọkàn wọn kò sòtítọ́ si i, wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú Rẹ̀ Ṣíbẹ̀ ó ṣàánú ó dárí àìṣedédé wọn jìn òun kò sì pa wọn run nígbà kí ì gbà ló ń dá ìbínú Rẹ̀ dúró kò sì rú ìbínú Rẹ̀ sókè Ó ránti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n, afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò le padà Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ síi ní ihà wọn mú-un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro! Síwájú àti síwájú wọn dán Ọlọ́run wò wọ́n mú ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì bínú Wọ́n kò rántí agbára Rẹ̀ ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára, Ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ hàn ní Éjíbítì, àti iṣẹ́ àmì Rẹ ni ẹkùn Sáónì Ó ṣọ omi wọn dí ẹ̀jẹ̀ wọn kò le mú láti odò wọn Ó rán ọ̀wọ́ ẹṣinṣin láti pa wọ́n run, àti ọpọlọ tí ó bá wọn jẹun Ó fi ọkà wọn fún láńtata àwọn irè oko wọn fún eṣú Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́ ó bá èso sìkàmore wọn jẹ́ Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná Ó mú kíkorò ìbínú Rẹ̀ wá sí wọn lára, ìrunú àti ikáánú, àti ìpọ́njú, nípa rírán ańgẹ́lì apanirun sí wọn Ó pèṣè ipa fún ìbínú Rẹ̀ òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-àrùn Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin Éjíbítì Olórí agbára wọn nínú àgọ́ Ámù Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn Rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran ó sọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú ihà Ó dáàbòbò wọ́n dáadáa, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n ṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn Bákan náà ní ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ Rẹ òkè tí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ tí gbà Ó lé orílẹ̀ èdè jáde níwájú wọn ó sì pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní ó mú àwọn ẹ̀yà Íṣírẹ́lì jókòó ní ilẹ̀ wọn Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo wọn kò pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́ Gẹ́gẹ́ bí baba wọn, wọn jẹ́ aláìsòdodo gẹ́gẹ́ bi ọrun ẹ̀tàn Wọ́n bí nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn wọn rú owú Rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn, inú bí i gidigidi ó kọ Ísírẹ́lì pátapáta Ó kọ àgọ́ Ṣílò sílẹ̀, àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára Rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn, dídán ògo Rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá Ó fi àwọn ènìyàn Rẹ̀ lé idà lọ́wọ́, ó sì bínú sí àwọn ohun ìní Rẹ̀ Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn, àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó A fi àlùfáà wọn fún idà, àwọn opó wọn kò sì le è sunkún Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jù kúrò nínú ìraníyè ọtí Ó kọlu àwọn ọta Rẹ̀ padà ó fí wọn sínú ìtìjú ayérayé Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Jósẹ́fù, kò sì yan ẹ̀yà Éfúráímù Ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Júdà, òkè Síónì, èyí tí ó fẹ́ràn Ó kọ́ ibi mímọ́ Rẹ̀, ibí gíga, gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé Ó yan Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀ ó mú láti inú àwọn agbo ẹran Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn láti jẹ́ olùṣọ́ Àgùntàn àwọn ènìyàn Rẹ̀ Jákọ́bù àti Ísírẹ́lì ogún un Rẹ̀ Dáfídì sì ṣọ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn pẹ̀lú ọwọ́ òye ní ó fi darí wọn Sáàmù 79 Ọlọ́run àwọn orílẹ̀ èdè ti wà ilẹ̀ ìní Rẹ wọn ti bá tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ jẹ́, wọn di Jérúsálẹ́mù kù sí òkìtì àlàpà Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ, ẹran ara àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀ Wọ́n tú ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi yí Jérúsálẹ́mù ká, kò sì sí àwọn tí yóò sìn wọ́n Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí o yí wa ká, àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wá ká Nígbà wo, Olúwa Ní ìwọ o máa bínú títí láé Yóò ti pẹ́ tó ti òwú Rẹ̀ yóò ha jò bi iná Tú ìbínú Rẹ̀ jáde sí orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀ Rẹ, lórí àwọn ìjọba tí kò pe orúkọ Rẹ Nítorí wọ́n ti run Jákọ́bù wọ́n sì sọ ibùgbé Rẹ̀ di ahoro Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùn jẹ́ kí àánú Rẹ yà kánkán láti bá wa, nítorí ti a Rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa, fún ògo orukọ Rẹ gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn nítorí orúkọ Rẹ Àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì máa wí pé, Níbo ni Ọlọ́run wọn wà ní ojú wa Kí a mọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè kí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí a tú jáde Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá ṣíwájú Rẹ, gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára Rẹ ìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bí ikú San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méje nípa ẹ́gàn tí wọn tí gàn ọ́ Olúwa Nígbà náà àwa ènìyàn Rẹ, àgùntàn pápá Rẹ, yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé láti ìran dé ìran ni àwa ó fi ìyìn Rẹ hàn Sáàmù 8 Olúwa , Olúwa wa, orúkọ Rẹ̀ ti tó tóbi tó ní gbogbo àyé! Ìwọ ti gbé ògo Rẹ̀ ga ju àwọn ọ̀run lọ Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀ta Rẹ, láti pa àwọn ọ̀ta àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́ Nígbà tí mo ro ọ̀run Rẹ, iṣẹ́ ìka Rẹ, òṣùpá àti ìràwọ̀, tí ìwọ tí gbé kalẹ̀, kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa Rẹ̀, ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú Rẹ̀ Ìwọ ṣeé ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju ẹ̀dá ọ̀run lọ ìwọ sì dée ní adé ògo àti ọlá Ìwọ mu-un jọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ ìwọ si fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀ gbogbo ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, àti ẹranko ìgbẹ́, ẹyẹ ojú ọrun, àti ẹja inú òkun, àti ohun tí ń wẹ nínú ipa òkun Olúwa , Olúwa wa, Orúkọ Rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé! Sáàmù 80 Gbọ́ tiwa, ìwọ olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì ìwọ tí ó darí Jósẹ́fù bí ọwọ́ ẹran ìwọ tí o jòkòó lórí ìtẹ́ láàrin Kérúbù, tàn jáde Níwájú Éfúremù, Bẹ́ńjámínì àti Mánásè Rú agbára Rẹ̀ sókè wa fún ìgbàlà wa Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run jẹ́ kí ojú Rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí a bà lé gbà wá là Olúwa Ọlọ́run, ìbínú Rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó sí àdúrà àwọn ènìyàn Rẹ Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn ìwọ ti mú wọn wa ẹ̀kún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa, àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run jẹ́ kí ojú Rẹ tàn sí wa, kí a ba à le gbà wá là Ìwọ mú àjàrà jáde láti Éjíbítì ìwọ lé àwọn aláìkọlà jáde, o sì gbìn-ín Ìwọ sí àyè sílẹ̀ fún un, ìwọ sì mu tọ gbòǹgbò jìnlẹ̀ ó sì kún ilẹ̀ náà A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjijì Rẹ̀, ẹ̀ka Rẹ dàbí kédárì Ọlọ́run O yọ ẹ̀ka Rẹ̀ sínú òkun, ọwọ́ Rẹ̀ sí odò ńlá nì Èéṣe tí ìwọ fi wó odi Rẹ̀ tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń sa èso Rẹ̀ Ìmọ̀do láti inú igbó ń bàá jẹ́ àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ, Ọlọ́run! Bo jú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó! Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò, Gbòngbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ ti gbìn, àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara Rẹ A gé àjàrà Rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún ní ìfibú, àwọn ènìyàn Rẹ̀ ń ṣègbé Jẹ́ kí ọwọ́ Rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ, ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbékalẹ̀ fún ara Rẹ Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ Rẹ mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ Rẹ Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run kí ojú Rẹ̀ kí o tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí á ba à lè gbà wá là Sáàmù 81 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jákọ́bù! Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́ Ẹ fún ìpè ni oṣù tuntun àní nígbà ti a yàn ní ọjọ́ àjọ wa ti ó ni ìrònú Èyí ni àṣẹ fún Ísírẹ́lì, àti òfin Ọlọ́run Jákọ́bù Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Jósẹ́fù nígbà tí ó la ìlẹ̀ Éjíbítì já níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa Ó wí pé, Mo gbé àjàgà kúro ní èjìká yín, a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀ Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là, mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá, mo dán an yín wò ní odò Méríbà Sela Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín, bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Ísírẹ́lì Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrin yín ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì Èmi ni Olúwa Ọlọ́run Rẹ, ẹni tí ó mú un yín jáde láti Éjíbítì Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi Ísírẹ́lì kò ní tẹríba fún mi Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi bí Ísírẹ́lì yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi, Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn kí ń sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn! Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú Rẹ̀ Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ́ yín èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta Sáàmù 82 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá, ó ṣe ìdájọ́ láàárin àwọn ọlọ́run òrìṣà Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìsòdodo kí ó sì ṣe ojú ìṣájú sí àwọn ènìyàn búburú Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní gbà wọ́n kùró lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú Wọn kò mọ̀ ohunkankan, wọn kò lóye ohunkankan Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn a ni gbogbo ìpínlẹ̀ ayé Mo wí pé, Ẹyin ní Ọlọ́run òrìṣà ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ ọ̀gá ògo jùlọ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin o kú bí ènìyàn lásán ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ aládé Dìde Ọlọ́run ṣe ìdájọ́ ayé, nítorí gbogbo orílẹ̀ èdè ni ìní Rẹ Sáàmù 83 Ọlọ́run, Má ṣe dákẹ́ Má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ ẹ́ Wo bí àwọn ọ̀tá Rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ, bi àwọn ọ̀tá Rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn Rẹ wọn gbìmọ̀ lòdì sí àwọn tí ó fẹ Wọn wí pé, wá, ẹ jẹ́ kí a pa wọn run bí orílẹ̀ èdè, kí orúkọ Ísírẹ́lì ma bá a sí ní ìrántí mọ́ Wọn gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ Àgọ́ Édómù àti ti àwọn ara Íṣímaélì, tí Móábù àti ti Hágárì Gébálì, Ámónì àti Ámálékì, Fílítísitíà, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tirẹ̀ Áṣurí pẹ̀lú tí darapọ̀ mọ́ wọn láti ràn àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́ Sela Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Mídíánì bí o ti ṣe sí Sísérà àti Jábínì ní òdò Kíṣíónì, Ẹni tí ó ṣègbé ní Éndórí tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀ Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orébù àti Séébù, àwọn ọmọ aládé wọn bí Ṣébà àti Sálmúnà, Tí ó wí pé, Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní Ẹni pápá oko tútù Ọlọ́run Ìwọ Ọlọ́run, Ṣe wọn bí ààjà, bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́ Bí ìna ti i jó ìgbẹ́ ìgbó àti bí ọ̀wọ́ iná ti ń mú òkè-ńlá gbiná, Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle Rẹ lépa wọn ja wọn lójú pẹ̀lú ìjì Rẹ fi ìtìjú kún ojú wọn kí àwọn ènìyàn báà lè ṣe àfẹ́rí orúkọ Rẹ àti kí o fí ìjì líle Rẹ dẹ́rùbà ìwọ Olúwa Jẹ́ kí ojú kí ó ti wọn, kí wọ́n sì dáámù láéláé kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ Rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa pé ìwọ níkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé Sáàmù 84 Ibùgbé Rẹ̀ ti lẹ́wà tó, Olúwa Olódùmarè! Ọkàn mí ń fà nítòótọ́ ó tilẹ̀ pòùngbẹ fún àgbàlá Olúwa àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọ́run alààyè Nítòotọ́ ologóṣẹ ri ilé, ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara r, níbi tí yóò máa pá ọmọ Rẹ̀ mọ́ sí ibùgbé ní tòsí pẹpẹ Rẹ, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé Rẹ wọn o máa yìn ọ́ títí láé Ìbùkún ní fún àwọn tí agbára wọn wà nínú Rẹ àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò Àwọn tí ń la àfonífojì omije lọ wọn sọ ọ́ di kànga àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá títí tí ọ̀kọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Síónì Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jákọ́bù Wo àsà wa, Ọlọ́run fi ojú àánú wò àwọn ẹni àmì òroro Rẹ Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin Rẹ ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi ju láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrun àti àṣà Olúwa fúnni ní ojúrere àti ọlá kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn dádúró fún àwọn tí o rin ní aílábùkù Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ Sáàmù 85 Ìwọ fi ojú rere han fún ilé Rẹ, Olúwa ìwọ mú ohun ìní Jákọ́bù bọ̀ sí pò Ìwọ dárí àìṣedédé àwọn ènìyàn Rẹ̀ jìn ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀ Sela Ìwọ fi àwọn ìbínú Rẹ sápá kan ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná Rẹ Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa, kí o sì yí ìbínú Rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé Ìwọ yóò ha mú ìbínú Rẹ pẹ́ yìí gbogbo ìran ká Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́, pé kí àwọn ènìyàn Rẹ lè yọ nínú Rẹ Fi ìfẹ́ Rẹ tí kò le e kùnà hàn wá, Olúwa , Kí o sì fún wa ní ìgbàlà Rẹ Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn Rẹ̀, àní ẹni mímọ́ Rẹ̀ Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmòye Nítòótọ́ ìgbàlà Rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀, pé kí ògo Rẹ̀ kí ó le gbé ní ilẹ̀ wa Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀ òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá òdodo sì bojúwolẹ̀ láti ọ̀run Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́, ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè Rẹ̀ jáde Òdodo ṣíwájú Rẹ lọ o sì pèṣè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ Rẹ̀ Sáàmù 86 Gbọ́, Olúwa , kí o sì dà mí lóhùn, nítorí mo jẹ́ talákà àti aláìní Dáàbòbò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ ìwọ ní Ọlọ́run mi, gbà ìránṣẹ́ Rẹ là tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ Ṣàánú fún mi, Olúwa , nítorí èmi ń pe ọ́ ní gbogbo ọjọ́ Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ Rẹ, nítorí ìwọ, Olúwa , ní mo gbé ọkan mí sókè sí Ìwọ ń daríjì, ìwọ sì dára, Olúwa , ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn ti ń ké pè ọ́, Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa tẹ́tí sí ẹkún fún àánú Ní ọjọ́ ipọ́njú mi èmi yóò pe ọ́, nítorí ìwọ yóò dá mí lóhùn Nínú àwọn òrìṣà kò sì ẹni tí ó dà bí Rẹ, Olúwa kò sí àwọn iṣẹ́ tí a le fi wé tìrẹ Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ dá yóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú Rẹ, Olúwa wọn o mú ògo wà fún orúkọ Rẹ̀ Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ si ń ṣe ohun ìyanu ìwọ nìkan ní Ọlọ́run Kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ, Olúwa , èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ Rẹ fún mi ní ọkàn tí kì í yapa, kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ Rẹ Èmi o yìn ọ, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkan mi èmi o fògo fún orúkọ Rẹ títí láé Nítorí títóbi ní ìfẹ́ Rẹ̀ si mi ìwọ ti gba mí kúrò nínú ọ̀gbun ìsà okú Àwọn onígbéraga ń dojú kọ mí, Ọlọ́run àti ìjọ̀ àwọn alágbára ń wá ọkàn mi kiri, wọn kò sì fi ọ pè Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa , jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere, Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́ Yípadà sí mi kí ó sì ṣàánú fún mi fún àwọn ènìyàn Rẹ ní agbára kí o sì gba ọ̀dọ́mọ̀kunrin ìránṣẹ́-bìnrin Rẹ là Fi àmi hàn mí fun rere, kí àwọn tí ó kóriíra mi le rí, ki ojú le tì wọ́n, nítorí iwọ ni ó ti tù mi nínú Sáàmù 87 Ó ti fi ìpilẹ̀ Rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́ Olúwa fẹ́ràn ẹnu ọ̀nà Síónì ju gbogbo ibùgbé Jákọ́bù lọ Ohun ológo ni a sọ nípa Rẹ, ilú Ọlọ́run Èmi ó dárúkọ Rákábù àti Bábílónì láàrin àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi Fílístínì pẹ̀lú, àti Tirẹ, pẹ̀lú Kúṣì yóò sọ pé, èyí ni a bí ni Síónì Nítòótọ́, tí Síónì ni a ó sọ, Eléyìí àti eléyì í ni a bí nínú Rẹ̀, àti Ọlọ́run Ọ̀gá ògo ni yóò fìdí Rẹ̀ múlẹ̀ Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀ Eléyìí ni a bí ní Síónì Àti àwọn olorin àti àwọn ti ń lu ohun èlò orin yóò wí pé, Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú Rẹ Sáàmù 88 Olúwa , Ọlọ́run tí o gba mí là, ní ọ̀sán àti ní òru ni mo kígbe sókè sí Ọ Jẹ́ kí àdúrà mi kí o wá sí iwájú Rẹ dẹ etí Rẹ̀ sí igbe mi Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀ èmi dà bí ọkùnrin tí kò ni agbára A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú, ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́, ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jínjìn, ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn Ìbínú Rẹ ṣubú lé mi gidigidi ìwọ ti fi àwọn ìjì Rẹ̀ borí mi Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mí kúrò lọ́wọ́ mi ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn A há mi mọ́, èmi kò sì lé è jáde Ojú mi káànú nítorí ìpọ́njú Mo kígbe pè ọ́, Olúwa , ní gbogbo ọjọ́ mo na ọwọ́ mí jáde sí ọ Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu Rẹ hàn fún òkú Àwọn òkú yóò ha dìde láti yín ọ́ bí A ó ha fi iṣeun ifẹ́ Rẹ hàn ni ibojì bí Tàbí òtítọ́ Rẹ ni ipò iparun A ha le mọ iṣẹ́ ìyanu Rẹ ní òkùnkùn bí àti òdodo Rẹ ní ìlà ìgbàgbé Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa ní òwúrọ̀ ní àdúrà mí wá sọ́dọ̀ Rẹ Olúwa , èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí tí ìwọ fi ojú Rẹ pamọ́ fún mi Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi, èmi múra àti kú nígbà ti ẹ̀ru Rẹ ba ń bà mí, èmi di gbére-gbère Ìbínú Rẹ ti kọjá lára mi ìbẹ̀rù Rẹ ti ge mi kúrò Ní gbogbo ọjọ́ ní wọn yí mi ká bí ìkún omi wọ́n mù mí pátápátá Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi Sáàmù 89 Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ̀ òtítọ́ Rẹ láti ìran dé ìran Èmi ó wí pé, ìfẹ́ Rẹ dúró títí láé, pe ìwọ gbe òtítọ́ Rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnrarẹ Ìwọ wí pé, Èmi ti dá májẹ̀mu pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi mo ti búra fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi Èmi ó fi ìdí irú ọmọ Rẹ múlẹ̀ títí láé èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ Rẹ ró láti ìran dé ìran Àwọn ọ̀run yóò mú yín ṣiṣẹ́ ìyanu Rẹ, Olúwa , òtítọ́ Rẹ ní ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́ Ta ní ó wà ni ọ̀run ti a lè fi we Olúwa Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fi wé Olúwa Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọn bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi ó sì ní ibùyìn fún jú gbogbo àwọn tí ó yí i ká Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí Rẹ ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa , òtítọ́ Rẹ sì yí ọ ká Ìwọ ń darí ríru omi òkun nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn pa rọ́rọ́ Ìwọ ni o ti ya Ráhábù pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí ẹni tí a pa ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára Rẹ tú àwọn ọ̀tá Rẹ ká Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ tìrẹ ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú Rẹ̀ ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀ Gúṣù àti Àríwá ìwọ ní ó dá wọn Taborí àti Hámónì ń fi ayọ̀ yìn orúkọ Rẹ Ìwọ ní apá agbára agbára ní ọwọ́ Rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ Òdodo àti òtítọ́ ní ìpílẹ̀ ìtẹ́ Rẹ ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ ṣíwájú Rẹ Ìbùkún ní fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ igbe ayọ̀, tí ó ń rìn Olúwa nínú ìmọ́lẹ̀ oju Rẹ Wọn ń ṣògo nínú orúkọ Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́, wọn ń yin òdodo Rẹ Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn nípa ojúrere ni ìwọ wá ń ṣògo Nítorí tí Olúwa ni asà wa, ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì Nígbà náà ní ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran sí àwọn olótítọ́ Rẹ, wí pé èmi tí gbé adé kálẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára, èmi ti gbé ẹni tí a yan láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga Èmi tí rí Dáfídì ìránṣẹ́ mi pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ní mo fi yàn án Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú Rẹ̀ a pá mí yóò sì fi agbára fún un Àwọn ọ̀tá kí yóò borí Rẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò Rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ Èmi yóò run àwọn ọ̀tá Rẹ níwájú Rẹ èmi yóò lu àwọn tí ó kóríra Rẹ bolẹ̀ Òtítọ́ mi àti ìdúróṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú Rẹ àti ní orúkọ mi ní a ó gbé ìwo Rẹ ga Èmi o gbé ọwọ́ Rẹ lórí òkun àti ọwọ́ ọ̀tún Rẹ lórí àwọn odo ńlá Òun yóò kígbe sí mi pé, ìwọ ní bàbá mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi! Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mí, Ẹni gíga jù àwọn ọba ayé Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un, àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin Èmi o fi ìdí irú ọmọ Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé, àti ìtẹ́ Rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé Bí àwọn ọmọ Rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀ tí wọ́n kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi Tí wọn bá kọ ìlànà mi tí wọ́n kò sì pa àṣẹ mi mọ́, Nígbà náà ni èmi o fì ọ̀gà bẹ irékọjá wọn wò àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú ìná Ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ Rẹ, tàbí ṣẹ́ tán sí òtítọ́ mi Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mí, tàbí kí èmi yí ọ̀rọ̀ tí o ti ẹnu mi jáde padà Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ní èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra èmi kì yóò purọ́ fún Dáfídì Irú ọmọ Rẹ yóò dúró títí láé, àti ìtẹ́ Rẹ̀ yóò dúró bí òòrùn níwájú mi A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá, àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run Sela Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ìwọ ti sá tì, ìwọ sì kórìíra ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró Rẹ Ìwọ tì sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ Rẹ di òfo ìwọ tàbùkù adé Rẹ nínú ilẹ Ìwọ tí wo gbogbo àwọn odi Rẹ̀ ìwọ sọ ibi gíga Rẹ̀ di ahoro Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ o ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé e Rẹ̀ Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá Rẹ̀ sókè ìwọ mú gbogbo ọ̀tá Rẹ̀ yọ̀ Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà Rẹ̀ padà, ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun Ìwọ ti mú ògo Rẹ̀ kùnà, ìwọ si wó ìtẹ́ Rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀ Ìwọ ti gé ọjọ́ èwé Rẹ̀ kúrú ìwọ si fi ìtìjú bò ó Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa Tí ìwọ ó ha fi ara Rẹ pamọ́ títí láé Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú Rẹ yóò máa jó bí iná Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó nítorí asán ha ní ìwọ fi sẹ̀dá àwọn ènìyàn! Ta ni yóò wà láàyè tí kò ní rí ìkú Rẹ̀ Ta lo lé sa kúrò nínú agbára isà-òkú Olúwa , níbo ni ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àtijọ́ wà, tí ìwọ ti fi òtítọ́ Rẹ̀ búra fún Dáfídì Rántí, Olúwa , bí àti ń gan àwọn ìránṣẹ́ Rẹ bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, Ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá Rẹ gàn, Olúwa , tí wọn gan ipaṣẹ̀ Ẹni àmì òróró Rẹ Olùbùkún ní Olúwa títí láé Àmín àti Àmín Sáàmù 9 Èmi o yìn ọ, Olúwa , pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi Èmi o sọ ti ìyanu Rẹ gbogbo Inú mi yóò dùn èmi yóò sì yọ̀ nínú Rẹ Èmi o kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ Àwọn ọ̀ta mi pẹ̀yìndà Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú Rẹ Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ Rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo Ìwọ ti bá orílẹ̀ èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀ta, Ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu Àní ìrántí wọn sì ti sègbé Olúwa jọba títí láé ó ti gbé ìtẹ́ Rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́ Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àyé ní òdodo yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú Àwọn tí ó mọ orúkọ Rẹ yóò gbà ọ́ gbọ́, èmi tàbí ìwọ, Olúwa , kò kọ àwọn to ń wa a sílẹ̀ Kọ orin ìyìn sí Olúwa , ti o ń jọba ní Síónì kéde láàrin àwọn orílẹ̀ èdè ohun tí o ṣe Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú Olúwa , wo bí àwọn ọ̀ta ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi! Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu ọ̀nà ikú, Kí èmi kí o lè sọ ti ìyìn Rẹ ni ẹnu ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Síónì àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà Rẹ Àwọn orílẹ̀ èdè ti jìn sí kòtò ti wọn ti gbẹ́ ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́ A mọ Olúwa nípa òdodo Rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú, àti gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a ò ní gbàgbé láéláé, ìrètí àwọn ti ó talakà lójú kí yóò ṣègbé láéláé Dìde, Olúwa , má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀ èdè ni iwájú Rẹ Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n Sela Sáàmù 90 Olúwa , ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìrán dé ìran Kí a to bí àwọn òkè nla àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé, láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀, wí pé padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú Rẹ, bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru Ìwọ gbá ènìyàn dánù nínú oorun ikú wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀ Lótìítọ́ ní òwúrọ́ ó yọ tuntun ní àsálẹ́ ní yóò gbẹ tí yóò sì Rẹ̀ dànù A pa wá run nípa ìbínú Rẹ nípa ìbínú Rẹ ara kò rọ̀ wá Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú Rẹ, àti ohun ìkọ̀kọ̀ wà nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú Rẹ, Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú Rẹ àwa n lo ọjọ wá lọ bí àlá ti a ń rọ́ Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá, tí ó sì ṣe pé nipa agbára tí wọn bá tó ọgọrìn ọdún agbára wọn làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni nítorí pé a kò ni gé e kúrò, àwa a sì fò lọ Ta ni ó mọ agbára ìbínú Rẹ Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù Rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Rẹ Kọ́ wa bí a ti ń kàye ọjọ́ wa dáradára, kí àwa bá a le fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n Yípadà, Olúwa ! Yóò ti pẹ́ to Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ Tẹ́wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ Rẹ, kí àwa kí o le kọrin fún ayọ̀ kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́ Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú, fún ọjọ́ pípọ̀ tí àwa ti rí wàhálà Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ Rẹ̀ hàn àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ògo Rẹ̀ sì àwọn ọmọ wọn Jẹ́ kí ẹwa Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa fí ìdí iṣẹ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa bẹ́ẹ̀ ní kí ó sì ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ Sáàmù 91 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ ọ̀gá ògo ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé, Òun ní ààbò àti odi mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé Ní tòótọ́ òun yóò gbà mí nínú ìdẹkùn àwọn pẹyẹ pẹyẹ àti nínú àjàkálẹ̀-àrùn búburú Òun yóò fi ìyẹ́ Rẹ̀ bò mí, àti ni abẹ́ ìyẹ́ Rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò òtítọ́ Rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru, tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán, Tàbí fún àjàkálẹ̀-àrùn tí ń rìn kiri ni òkùnkùn, tàbí fún ìparun ti ń rin kirí ni ọ̀sán gangan Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ Rẹ, ẹgbàarùn ún ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ ṣùgbọ́n kì yóò sún mọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú Rẹ àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò Rẹ, ìwọ fi Ọ̀ga Ògo ṣe ibùgbé Rẹ Búburú kan ki yóò subu lù ọ́ Bẹ́ẹ̀ ni àrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé Rẹ Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì nípa tìrẹ láti pa ọ́ mọ ní gbogbo ọ̀nà Rẹ Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn, nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ Rẹ̀ gún òkúta Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀ ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò nì ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀ Nítorí tí ìfẹ́ Rẹ sì mi, èmi yóò gbà ọ́ èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dáa lóhùn èmi yóò wà pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ipọ́nju, èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án Sáàmù 92 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa àti láti máa kọrin sí orúkọ Rẹ̀, Ọ̀gá ògo, Láti kéde ìfẹ́ Rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti òtítọ́ Rẹ̀ ní alẹ́ Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá àti lára ohun èlò orin háàpù Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ Rẹ Olúwa èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ Báwo ni isẹ́ Rẹ tí tóbi tó, Olúwa , èrò inú Rẹ ìjìnlẹ̀ ni! Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n, aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n, Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú, wọn yóò run láéláé Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá Rẹ, Olúwa , nítòótọ́ àwọn ọ̀ta Rẹ yóò ṣègbé gbogbo àwọn olùṣe búburú ní a ó fọ́nká Ìwọ tí gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó òróró dídára ni a dà sími ní orí Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀ta mi ìparun sí àwọn ènìyàn búburú tí ó dìde sí mi Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ, wọn yóò dàgbà bí i igi kédárì Lẹ́bánónì Tí a gbìn si ilé Olúwa , Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini, Láti fihàn pé Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa òun ni àpáta mi, kò sì sí aburú kankan nínú Rẹ̀ Sáàmù 93 Olúwa ń jọba, ọlá ńlá ní ó wọ̀ ní aṣọ ọlá ńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ àti ìhàmọ́ra Rẹ̀ pẹ̀lú agbára Ó fi ìdí ayé múlẹ̀ kò sì le è yí Ìjọba Rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́ ìwọ wà títí ayé raye A ti gbé òkun sókè, Olúwa , òkun ti gbé ohùn wọn sókè òkun ti gbé rírú omi wọn sókè Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ, ó ni ògo ju òkun rírú lọ Olúwa ga ní ògo Ẹ̀rí Rẹ̀ dúró ṣinṣin ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé Rẹ̀ lọ́sọ̀ọ́ fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa Sáàmù 94 Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san, Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san Gbé ara Rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé san ẹ̀san fún agbéraga ohun tí ó yẹ wọ́n Báwo ní yóò ti pẹ́ tó, Olúwa tí àwọn ẹni búburú yóò kọ orin ayọ̀ Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbérága jáde gbogbo àwọn olùṣebúburú kún fún ìṣògo Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn Rẹ túútúú, Olúwa wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní Rẹ̀ lójú Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò, wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba, Wọ́n sọ pé, Olúwa kò rí i Ọlọ́run Jákọ́bù kò sì kíyèsí i Kíyèsí i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bi Ẹni tí ó dá ojú Ó ha lè ṣe láìríran bi Ẹni tí ń bá orílẹ̀ èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni sọ́nà bí Ẹni ti ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí Olúwa mọ èrò inú ènìyàn ó mọ̀ pé aṣán ni wọ́n Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ìwọ báwí, Olúwa , ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin Rẹ Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi, títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú Nítorí Olúwa kò ní kọ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀ Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní Rẹ̀ sílẹ̀ Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo, àti gbogbo àwọn ọlọ́kàn dídúró ṣinṣin yóò tẹ̀ lé e lẹ́yìn Ta ni yóò dìde fún mi sí àwọn olùṣe búburú Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́, èmi fẹ́rẹ̀ má a gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́ Nígbà tí mo sọ pé ẹsẹ̀ mi ń yọ̀, Olúwa , ìfẹ́ Rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi, ìtùnú Rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Rẹ ẹni tí ń fí òfin dìmọ̀ ìwà ìkà Wọ́n kó ara wọn jọ si olódodo wọ́n sì ń dá àwọn aláìsẹ̀ lẹ́bi sí ikú Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi, àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni tí mo ti ń gba ààbò Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run Sáàmù 95 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa Ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa Ẹ jẹ́ kí a wá sí ìwájú Rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ kí a sì pòkìkí Rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò orin àti ìyìn Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni, ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ Ní ọwọ́ Rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà, ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe Tirẹ̀ ni òkun, nítorí òun ni ó dá a àti ọwọ́ Rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀ Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a forí balẹ̀ kí a sìn-ín, Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú Olúwa ẹni tí ó dá wa Nítorí òun ni Ọlọ́run wa àwa sì ni ènìyàn pápá Rẹ̀, àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ Rẹ̀ Lónìí ti ìwọ bá gbọ́ ohùn Rẹ̀, Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Méríbà, àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ni Másà ni ihà, Nígbà ti àwọn baba yin dán mi wò ti wọn wádìí mi, ti wọn sì ri iṣẹ́ mi Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà mo wí pé, Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn sáko lọ wọn kò sì mọ ọ̀nà mi Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi Sáàmù 96 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé Ẹ kọrin sí Olúwa , yin orúkọ Rẹ̀ ẹ sọ ti ìgbàlà Rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́ Ẹ sọ ti ògo Rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè àti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ láàrin gbogbo ènìyàn Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ sí òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìsà lọ Nítorí aṣán ni gbogbo àwọn òrìsà orílẹ̀ èdè ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run Ọlá àti ọlá ńlá wà ni ìwájú Rẹ̀ agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ Rẹ̀ Ẹ fi fún Olúwa , ẹ yin ìbátan ènìyàn Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa Ẹ fi ògo tí o tọ́ sí Olúwa fún un ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá Rẹ̀ Ẹ máa sin Olúwa ninú ẹwà ìwà mímọ́ Rẹ̀ ẹ wárìrì níwájú Rẹ̀ gbogbo ayé Sọ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, Olúwa jọba a fi ìdí ayé mú lẹ̀, tí kò sì lè yí ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì dùn jẹ́ kí òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun gbogbo tí ń bẹ nínú Rẹ̀ Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀ àti ohun gbogbo ti ń bẹ nínú Rẹ̀ nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀ Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa , nítorí ti ó ń bọ́ wá, òun bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fí òtítọ́ Rẹ̀ ṣe Sáàmù 97 Olúwa jọba, jẹ́ kí ayé kí o yọ̀ jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yí ká òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ Rẹ̀ Iná ń jó níwájú Rẹ̀ O sì ń jó àwọn ọ̀ta Rẹ̀ yíká kiri Ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn ó sí kárí ayé ayé rí i ó sì wárìrì Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa , níwájú Olúwa gbogbo ayé Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo Rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo Rẹ̀ Gbogbo àwọn tí ń sin òrìṣà ni ojú yóò ti, àwọn ti n fi ère ṣe àfẹ́rí ara wọn Ẹsìn ín, ẹ̀yin òrìṣà Síónì gbọ́, inú Rẹ̀ sì dùn ìnú àwọn ilé Júdà sì dùn Nítorí ìdájọ́ Rẹ, Olúwa Nítorí pé ìwọ, Olúwa , ní ó ga ju gbogbo ayé lọ ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìsà lọ Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa , kórira ibi, ó pa ọkan àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ mọ́ ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn Ẹ yọ̀ nínú Olúwa , ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo, kí ẹ sì yin orúkọ Rẹ̀ mímọ́ Sáàmù 98 Ẹ kọrin túntún sí Olúwa , nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ àti apa mímọ́ Rẹ̀ o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un Olúwa ti sọ ìgbàlà Rẹ̀ di mímọ̀ o fí òdodo Rẹ̀ han àwọn orílẹ̀ èdè Ó rántí ìfẹ́ Rẹ̀ àti òtítọ́ Rẹ̀ fún àwọn ará ilé Ísírẹ́lì gbogbo òpin ayé ni ó ti rí iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa , gbogbo ayé, ẹ bu sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa , pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́, Pẹ̀lú ìpè àti fèrè ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa Ọba Jẹ́ kí òkun kí o hó pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú Rẹ̀, Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú Rẹ̀ Ẹ jẹ́ kí odo kí ó sápẹ́, ẹ jẹ́ kí òkè kí o kọrin pẹ̀lú ayọ̀ Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa Nítorí tí yóò wá ṣè dájọ́ ayé bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú Sáàmù 99 Olúwa jọba jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì o jòkòó lórí ìtẹ́ kérúbù jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì Olúwa tóbi ní Síónì o sì ga jù gbogbo orílẹ̀ èdè lọ Kí wọ́n sì yín orúkọ Rẹ̀ tí ó tóbi tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni òun Olúwa tóbi lọba, ó fẹ́ òdodo ó dá ìdọ́gba sílẹ̀ ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí o yẹ nínú Jákọ́bù Gbígbé ga ní Olúwa Ọlọ́run wa ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹṣẹ̀ Rẹ̀ ó jẹ́ mímọ́ Mósè àti Árónì wà nínú àwọn àlùfáà Rẹ̀ Sámúẹ́lì wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ Rẹ̀ wọ́n képe Olúwa , ó sì dá wọn lóhùn Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀, wọ́n pa ẹrí Rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedédé wọn jẹ wọ́n Gbígbé ga ni Olúwa Ọlọ́run wa kí a sìn ín ní òkè mímọ́ Rẹ̀ nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́ Ọ̀rọ̀ Ìsáájú Ìfihàn ti Jésù Kírísítì, tí Ọlọ́run fi fún un, láti fi hàn fún àwọn ìranṣẹ́ rẹ̀, ohun tí kò le ṣàìsẹ ní lọ́ọ́lọ́ ó sì ránṣẹ́, ó sì fi í hàn láti ọwọ́ ańgẹ́lì rẹ̀ wá fún Jòhánù, ìránṣẹ́ rẹ̀ Ẹni tí ó jẹ́rìí ohun gbogbo tí ó rí—èyí ì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti ẹ̀rí ti Jésù Kírísítì Olúkúlùkù ni ẹni tí ń kà, àti àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ̀lẹ̀ yìí, tí ó sì ń pa nǹkan wọ̀n-ọ́n-nì tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́ nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀ Jòhánù, Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Éṣíà Ore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀ Àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Kírísítì, ẹlẹ́rì olóòótọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, Tí ó sì ti fi wá jẹ ọba àti àlùfáà láti sin Ọlọ́run àti Baba rẹ tirẹ̀ ni ògo àti ìjọba láé àti láéláé Àmín Kíyèsí i, Ó ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀ gbogbo ojú ni yóò sì rí i, àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ náà ni Àmín Èmi ni Álfà àti Òmégà, ni Olúwa Ọlọ́run wí, ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, Olódùmarè Èmi, Jòhánù, arákùnrin yín àti alábàápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jésù, wà ní erekùsù tí a ń pè ní Patimo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jésù Kírísítì Mo wà nínú Ẹ̀mí ní ọjọ́ Olúwa, mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ̀yìn mi, bí ìró ipè, Ó ń wí pé, Èyí tí ó wí pé, kọ̀wé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje sí Éfésù, àti sí Simirínà, àti sí Párágámù, àti sí Tíátírà, àti sí Sarádì, àti sí Filadéfíà, àti sí Laódíkéà Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀ Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje Àti láàrin àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dà bí ọmọ ènìyàn, tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹṣẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́ Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí Sínóò ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná Ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀ Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde Ojú rẹ̀ sì dàbí òòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹṣẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú Ó si fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, Máṣe bẹ̀rù Èmi ni ẹni-ìṣájú àti ẹni-ìkẹyìn Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láàyè, tí ó sì ti kú sì kíyèsí i, èmi sì ń bẹ láàyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò-òkú Kọ̀wé nítorí náà ohun tí ìwọ ti rí, àti ti ohun tí ń bẹ, àti ti ohun tí yóò hù lẹ́yìn èyí Ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà Ìràwọ̀ méje ni àwọn ańgẹ́lì ìjọ méje náà àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje Àwọn Ańgẹ́lì Àti Ìwé Kékeré Mó sì rí ańgẹ́lì mìíràn alágbára ò ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, a fi awọsànmà wọ̀ ọ́ ni aṣọ òṣùmàrè sì ń bẹ ní orí rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dàbí òòrùn, àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ bí ọ̀wọ́n iná Ó sì ní ìwé kékeré kan tí a sí ní owọ́ rẹ̀ ó sì fi ẹṣẹ rẹ̀ ọ̀tún lé òkun, àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ òsì lé ilẹ̀ Ó sì ké lóhùn rara, bí ìgbà tí kìnnìún bá bú ramúramù Nígbà tí ó sì ké, àwọn àrá méje náà fọhùn Nígbà tí àwọn àrá méje fọhùn, mo múra àti kọ̀wé mo sì gbọ ohùn láti ọ̀run wá ń wí fún pé, Fi èdìdì di ohun tí àwọn àrá méje náà sọ, má sì ṣe kọ wọ́n sílẹ̀ Ańgẹ́lì náà tí mo rí tí ó dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀, sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run Ó sì fi ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láé láé búra, ẹni tí o dá ọ̀run, àti ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀, pé, Kí a má ṣe jáfara mọ́ Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ohùn ìpè ańgẹ́lì kéje, nígbà tí yóò ba fún ìpè, nígbà náà ni ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí o tí sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì ni a ó mú ṣẹ Ohùn náà tí mo gbọ́ láti ọ̀run tún ń ba mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé, Lọ, gba ìwé tí a ṣí náà lọ́wọ́ ańgẹ́lì tí o dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀ Mo sì tọ ańgẹ́lì náà lọ, mo sì wí fún pé, Fún mi ní ìwé kékeré náà Ó sì wí fún mi pé, Gbà kí o sì jẹ ẹ́ tan yóò dàbí oyin   Mo sì gba ìwé kékeré náà ni ọwọ́ ańgẹ́lì náà mo sì jẹ ẹ́ tan ó sì dùn lẹ́nù mi bí oyin bí mo sì tí jẹ ẹ́ tan, inú mi korò A sì wí fún mi pé, Ìwọ ó sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn, àti orílẹ̀ àti èdè, àti àwọn ọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Méjì A sì fi ìféèfé kan fún mi tí o dàbí ọ̀pá ẹnìkan sì wí pé, Dìde, wọn tẹ́ḿpílì Ọlọ́run, àti pẹpẹ, àti àwọn tí ń sìn nínú rẹ̀ Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹ́ḿpìlì sílẹ̀, má si ṣe wọ̀n ọ́n nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjì lé lógójì Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ̀rìí mi méjèèje, wọn o sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fa ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta nínú aṣọ-ọ̀fọ̀ Wọ̀nyí ni igi olífì méjì náà, àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ń dúró níwájú Olúwa ayé Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọn lara, iná ó ti ẹnu wọn jáde, a sì pa àwọn ọ̀ta wọn run bayìí ni a ó sì pa ẹnikẹ́ni tí ó ba ń fẹ́ pa wọn lára run Àwọn wọ̀nyí ni ó ni agbára láti sé ọ̀run, tí òjò kò fi lè rọ̀ ni ọjọ́ àsọtẹ́lẹ̀ wọn wọ́n sì ní agbára lórí omi láti sọ wọn di ẹ̀jẹ̀, àti láti fi onírúurú àjàkálẹ̀-àrùn kọlu ayé, nígbàkúgbà tí wọ́n bá fẹ́ Nígbà tí wọn bá sì ti parí ẹ̀rí wọn, ẹranko tí o ń tí inú ọ̀gbun gòkè wá yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n Òkú wọn yóò sì wà ni ìgboro ìlú ńlá náà tí a ń pè ní Sódómù àti Éjíbítì nípa ti ẹ̀mí, níbi tí a gbé kan Olúwa wọ́n mọ́ àgbélébùú Fún ijọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ ni àwọn ènìyàn nínú ènìyàn gbogbo àti ẹ̀yà, àti èdè, àti orílẹ̀, wo òkú wọn, wọn kò si jẹ kì a gbé òkú wọn sínú ibojì Àti àwọn tí o ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì yọ̀ lé wọn lórí, wọn yóò sì ṣe àríyá, wọn ó sì ta ara wọn lọ́rẹ nítorí tí àwọn wòlíì méjèèjì yìí dá àwọn tí o ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lóró, Àti lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí iyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ inú wọn, wọn sì dìde dúró ni ẹṣẹ̀ wọn ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí o rí wọn Wọn sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti ọ̀run wá ń wí fún wọn pé, Ẹ gòkè wá ìhín! Wọn sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú ìkúukúù àwọsánmà lójú àwọn ọ̀ta wọn Ní wákàtí náà ìmìmì-ilẹ̀ ńlá kan sì mì, ìdámẹ̀wàá ìlú náà sì wó, àti nínú ìmìmì-ilẹ̀ náà ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ènìyàn ní a pa ẹ̀rù sì ba àwọn ìyókù, wọn sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run Ègbé kéjì kọjá sì kìyèsí i, ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán Ańgẹ́lì kéje sì fọn ìpè a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé, Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kírísítì rẹ̀ òun yóò sì jọba láé àti láéláé! Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run, Wí pé Àwa fí ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè, tí ń bẹ, tí ó sì ti wà, nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀, ìwọ sì ti jọba Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ni ìbínú rẹ̀ ti dé, àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́, àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì, àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀, àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá àti láti run àwọn tí ń pa ayé run A sì ṣí tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run sílẹ̀ ní ọ̀run, a sì ri àpótí májẹ̀mu nínú tẹ́ḿpìlì rẹ̀ Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ilẹ́ sì mi, yìnyín ńlá sì bọ́ Obìnrin Kan Àti Dírágónì Àmì ńlá kan sì hàn ni ọ̀run obìnrin kan tí a fi òòrùn wọ̀ ní aṣọ, òṣùpá sì ń bẹ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá sì ń bẹ lórí rẹ̀ Ó sì lóyún, ó sì kígbe ni ìrọbí, ó sì wà ni ìrora àti bímọ Àmì mìíràn sì hàn lọ́run sì kíyèsí i, dírágónì pupa ńlá kan, tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, àti adé méje ní orí rẹ̀ Ìrù rẹ̀ sì wọ́ ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀, ó sì jù wọ́n sí ilẹ̀ ayé, dírágónì náà sì dúró níwájú obìnrin náà tí ó fẹ́ bímọ, pé nígbà tí o bá bí i, kí òun lè pa ọmọ rẹ̀ jẹ Ó sì bi ọmọkùnrin kan tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè a sì gba ọmọ rẹ̀ lọ sókè sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti sí orí ìtẹ́ rẹ̀ Obìnrin náà sì sá lọ sí ihà, níbi tí a gbé ti pèṣè ààyè sílẹ̀ dè é láti ọwọ́ Ọlọ́run wá, pé kí wọ́n máa bọ́ ọ níbẹ̀ ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta Ogun sì ń bẹ ní ọ̀run Mákẹ́lì àti àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun dírágónì sì jagun àti àwọn angẹ́lì rẹ̀ Wọ́n kò sì lè ṣẹ́gun Bẹ́ẹ̀ ni a kò sì rí ipò wọn mọ́ ni ọ̀run A sì lé dírágónì ńlá náà jáde, ejò láéláé ni, tí a ń pè ni Èṣù, àti Sàtanì, tí ń tan gbogbo ayé jẹ a sì lé e jù sí ilẹ̀ ayé, a sì lé àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú rẹ̀ Mo sì gbọ́ ohùn rara ní ọ̀run, wí pè Nígbà yìí ni ìgbàlà dé, àti agbára, àti ìjọba Ọlọ́run wá, àti ọlá àti Kírísítì rẹ̀ Nítorí a tí le olùfisùn àwọn arakùnrin wa jáde, tí o ń fí wọ́n sùn níwájú Ọlọ́run wa lọ́sàn-án àti lóru Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn, wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀mí wọn àní títí dé ikú Nítorí náà ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn Ègbé ni fún ayé àti òkun nítorí Èṣù sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá ní ìbínú ńlá, nítorí ó mọ̀ pé ìgbà kúkúrú ṣá ni òun ní Nígbà tí dírágónì náà rí pé a lé òun lọ sí ilẹ ayé, ó sè inúnibíni sì obìnrin tí ó bí ọmọkùnrin náà A sì fi apá iyẹ́ méjì tí ìdì ńlá náà fún obìnrin náà, pé kí ó fò lọ sí ihà, sí ipò rẹ̀, níbi tí a ó gbe bọ ọ fún àkókò kan àti fún àwọn àkókò, àti fún ìdajì àkókò kúrò lọ́dọ̀ ejò náà Ejò náà sì tu omi jáde láti ẹnu rẹ̀ wá bí odò ńlá sẹ́yìn obìnrin náà ki o lè fí ìṣàn omi náà gbà á lọ Ilẹ̀ sì ran obìnrin náà lọ́wọ́, ilẹ́ sì ya ẹnu rẹ̀, ó sì fi ìṣàn omi náà mú, tí dírágónì náà tu jáde láti ẹnu rẹ̀ wá Dírágónì náà sì bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn irú ọmọ rẹ̀ ìyókù jagun, tí wọ́n ń pa òfin Ọlọ́run mọ̀, tí wọn sì di ẹ̀rí Jésù mú, Ó sì dúró lórí ìyanrìn òkun Ẹranko Kan Tí Ń Ti Inú Òkun Jáde Wá Mo sì rí ẹranko kan ń ti inú òkun jáde wá, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, lórí àwọn ìwo náà ni orúkọ ọ̀rọ̀-òdì wà Ẹranko tí mo rí náà sì dàbí ẹkùn, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí tí béárì ẹnu rẹ̀ sì dàbí tí kìnnìún dírágónì náà sì fún un ni agbára rẹ̀, àti ìtẹ́ rẹ̀, àti àṣẹ ńlá Mo sì rí ọ̀kan nínú àwọn orí rẹ̀ bí ẹni pé a ṣá a pa, a sì tí wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ náà sàn, gbogbo ayé sì fi ìyanu tẹ̀lé ẹranko náà Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún dírágónì náà, nítorí tí o fún ẹranko náà ní àṣẹ, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, wí pé, Ta ni o dàbí ẹranko yìí Ta ni ó sì lè bá a jagun A sì fún un ni ẹnu láti má sọ ohun ńlá àti ọ̀rọ̀ òdì, a sì fi agbára fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni oṣù méjìlélógójì Ó sì ya ẹnu rẹ̀ ni ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rẹ̀, àti sí àgọ́ rẹ̀, àti sí àwọn tí ń gbé ọ̀run A sì fún-un láti máa bá àwọn ènìyàn-mímọ́ jagun, àti láti ṣẹ́gun wọn a sì fi agbára fún un lórí gbogbo ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti èdè, àti orílẹ̀ Gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì máa sìn ín, olúkúlúkù ẹni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀, sínú ìwé-ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn tí a tí pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé Bí ẹnikẹ́ni bá létí kí o gbọ́ Ẹni tí a ti pinnu rẹ̀ fún ìgbékùn, ìgbékùn ni yóò lọ ẹni tí a sì ti pinnu rẹ̀ fún idà, ni a ó sì fi idà pa Nihìn-ín ni sùúrù àti ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn mímọ́ wà Mo sì rí ẹranko mìíràn gòkè láti inú ilẹ̀ wá ó sì ní ìwo méjì bí Ọ̀dọ́-Àgùntàn, ó sì ń sọ̀rọ̀ bí dírágónì Ó sì ń lo gbogbo agbára ẹranko èkínní níwájú rẹ̀, ó sì mú ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ foríbalẹ̀ fún ẹranko èkínní tí a ti wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ sàn Ó sì ń ṣe ohun ìyanu ńlá, àní tí ó fi ń mú iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sì ilẹ̀ ayé níwájú àwọn ènìyàn Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fí fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà ó ń wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti yá àwòrán fún ẹranko náà ó ń wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti yá àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè A sì fi fún un, láti fi ẹ̀mí fún àwòrán ẹranko náà kí ó máa sọ̀rọ̀ kí ó sì mu kí a pa gbogbo àwọn tí kò foríbalẹ̀ fún àwòrán ẹranko náà Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti talákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba àmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn Àti kí ẹnikẹ́ni má lè rà tàbí tà, bí kò ṣe ẹni tí o bá ní àmì náà, èyí ni orúkọ ẹranko náà, tàbí àmì orúkọ rẹ̀ Niyìn ni ọgbọ́n gbé wà Ẹni tí o bá ní òye, kí o ka nọ́ḿbà tí ń bẹ̀ lára ẹranko náà nítorí pé nọ́ḿbà ènìyàn ni, nọ́ḿbà rẹ̀ náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta ọgọ́ta ẹẹ́fà Ọ̀dọ́-Àgùntàn Àti Oke Méje-ó-lé egbàá-méjì Mo sì wo, si kíyèsí i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Síónì, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje-ó-lé ẹgbàájì ènìyàn wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú-orí wọn Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí aríwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá mo sì gbọ́ àwọn oníháàpù, ń lù haàpù wọn Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin túntún níwájú ìtẹ́ náà, àti àwọn àgbà náà kò sì sí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn òkè méje o lé ẹgbàájì ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérì nítorí tí wọ́n jẹ́ wúndíá Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ Àwọn wọ̀nyí ni a ràpadà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ̀-Àgùntàn náà A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù Mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn ń fò ní àárin méjì ọ̀run, pẹ̀lú Ìyìn rere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn Ó ń wí ni ohùn rara pé, Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ogo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé ẹ sì foríbàlẹ́ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti òkun, àti àwọn orísun omi! Ańgẹ́lì mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, Ó ṣubú, Bábílónì ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀! Ańgẹ́lì mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, Bí ẹnikẹ́ni bá ń fóríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba àmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀ Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí-wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà láìní àbùlà sínú ago ìrúnnú rẹ̀ a ó sì fi iná sufúrù dá a lóró níwájú àwọn ańgẹ́lì mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba àmì orúkọ rẹ̀ Nihìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jésù mọ́ Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, Kọ̀wé rẹ̀ Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, Nítorí tí wọn yóò sìnmí kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkúùkùu àwọsánmà funfun kan, àti lóri ìkúùkùu àwọ̀sánmà náà ẹnikan jókòó tí o dàbí Ọmọ ènìyàn, tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀ Ańgẹ́lì mìíràn sì tí inú tẹḿpìlì jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkúùkùu àwọsánmà náà pé, Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán Ẹni tí ó jókòó lórí ìkúùkùu àwọsánmà náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé a sì ṣe ìkórè ilẹ̀ ayé Ańgẹ́lì mìíràn sì tí inú tẹmpílì tí ń bẹ ni ọ̀run jáde wá, òun pẹ̀lú sì ní dòjé mímú, kan Ańgẹ́lì mìíràn sì tí ibi pẹpẹ jáde wá, tí ó ní agbára lórí iná ó sì ké ni ohùn rara sí ẹni tí o ni dòjé mímú náà, wí pé, Tẹ dòjé rẹ mímú bọ̀ ọ́, ki ó sì rẹ̀ àwọn ìdí àjàrà ayé, nítorí àwọn èso rẹ̀ tí pọ́n Ańgẹ́lì náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ ilẹ́ ayé, ó sì gé àjàrà ilẹ́-ayé, ó sì kó o lọ sínú ìfúntì, ìfúntí ńlá ìbínú Ọlọ́run A sì tẹ ìfúntí náà lẹ́yìn òde ilú náà, ẹ̀jẹ̀ sì ti inú ìfúntí náà jáde, ó sì ga sókè dé okùn ìjánu ẹṣin, èyí tí ìnàsílẹ̀ rẹ to ẹ̀gbẹjọ̀ ibùsọ̀ Ańgẹ́lì Méje Pẹ̀lú Ìyọnu Méje Mo sì rí àmì mìíràn ní ọ̀run tí ó tóbi tí ó sì ya ni lẹ́nu, àwọn ańgẹ́lì méje tí ó ni àwọn ìyọnu méje ìkẹ́yìn, nítorí nínú wọn ni ìbínú Ọlọ́run dé òpin Mo sì rí bí ẹni pé, òkun dígí tí o dàpọ̀ pẹ̀lú iná àwọn tí ó sì dúró lórí òkun dígí yìí jẹ́ àwọn ti wọ́n sẹ́gun ẹranko náà, àti àwòrán rẹ̀, àti àmì rẹ̀ àti nọ́ḿba orúkọ rẹ̀, wọn ní Haàpù Ọlọ́run Wọ́n sì ń kọ orin ti Móṣè, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Olúwa Ọlọ́run Olodùmarè òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀, ìwọ Ọba àwọn orílẹ̀-èdè Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa, tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀ Nítorí ìwọ níkanṣoṣo ni mímọ́ Gbogbo àwọn orílẹ èdè mi yóò sì wá, ti yóò sì foribalẹ̀ níwájú rẹ, nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn Lẹ́yìn náà mo sì wo, sì kíyèsí i, a sí tẹ́ḿpìlì àgọ́ ẹ̀rí ní ọ̀run sílẹ̀ Àwọn ańgẹ́lì méje náà sì ti inú tẹ́ḿpìlì jáde wá, wọ́n ni ìyọnu méje náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun ti ń dán, a sì fi àmùrè wúrà dì wọ́n ni oókan àyà Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi àgbàda wúrà méje fún àwọn ańgẹ́lì méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé Tẹ́ḿpìlì náà sì kún fún èéfín láti inú ògo Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ wá ẹnikẹ́ni kò sì lè wọ inú tẹ́ḿpìlì náà lọ títí a fi mú ìyọnu méjèèje àwọn ańgẹ́lì méje náà ṣẹ Àwọn Aago Ìbínú Ọlọ́run Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti inú tẹ́ḿpìlì wá, ń wí fún àwọn ańgẹ́lì, méje nì pé, Ẹ lọ, ẹ sì tú ìgò ìbínú Ọlọ́run wọ̀nnì sí orí ayé Èkínní sì lọ, ó sì tú ìgò tirẹ̀ sí orílẹ̀ ayé egbò kíkẹ̀ tí ó sì díbàjẹ́ sì dá àwọn ènìyàn tí ó ní àmì ẹranko náà, àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ Èkejì sì tú ìgò sínú òkun ó sì dàbí ẹ̀jẹ̀ òkú ènìyàn gbogbo ọkàn alàyè sì kú nínú òkun Ẹ̀kẹ́ta sì tú ìgò tirẹ̀ sínú odò, àti sí orísun àwọn omi wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀ Mo sì gbọ́ ańgẹ́lì ti omi wí pé Olódodo ni ìwọ Ẹni Mímọ́ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, nítorí tí ìwọ ṣe ìdájọ́ báyìí Nítorí tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ àti ti àwọn wòlíì sílẹ̀, ìwọ sì fi ẹ̀jẹ̀ fún wọn mu èyí yìí ní ó yẹ wọ́n Mo sì gbọ́ pẹpẹ ń ké wí pé Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè, òtítọ́ àti òdodo ní ìdájọ́ rẹ Ẹ̀kẹrin sì tú ìgò tirẹ̀ sórí oòrùn a sì yọ̀ǹda fún un láti fi iná jó ènìyàn lára A sì fi oru ńlá jó àwọn ènìyàn lára, wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní agbára lórí ìyọnu wọ̀nyí wọn kò sì ronúpìwàdà láti fi ògo fún un Ẹ̀karùn-ún sì tú ìgo tirẹ̀ sórí ìtẹ ẹranko náà ilẹ̀ ọba rẹ̀ sì sókùnkùn wọ́n sì ń gé ahọ́n wọn jẹ́ nítorí ìrora Wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọ́n kò sì ronupìwàdà iṣẹ́ wọn Ẹ̀kẹfà sì tu ìgò tirẹ̀ sórí odò ńlá Yúfúrátè omi rẹ̀ sì gbẹ, kí a lè pèṣè ọ̀nà fún àwọn ọba láti ìlà òòrùn wá Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta bí ọ̀pọ̀lọ́, wọ́n ti ẹnu dírágónì náà àti ẹnu ẹranko náà àti ẹnu wòlíì èké náà jáde wá Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olúdàmarè Kíyèsí i ń bọ̀ bi olè, ìbùkún ni fún ẹni tí ń sọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́, kí ó mà bàá rìn ni ìhóhò, wọn a sì rí ìtìjú rẹ̀ Ó sì gbá wọn jọ́ sí ìbikan tí a ń pè ní Ámágédónì ní èdè Hébérù Èkeje si tú ìgo tírẹ̀ sí ojú ọ̀run ohùn ńlá kan sì ti inú tẹ́ḿpìlì jáde láti ibi ìtẹ́, wí pé, Ó parí! Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sì ṣẹ̀, irú èyí tí kò sẹ̀ ri láti ìgbà tí ènìyàn ti wà lórí ilẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀, tí ó sì lágbára tóbẹ́ẹ̀ Ìlú ńlá náà sì pín sí ipa mẹ́ta, àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú Bábílónì ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un Olúkúlùkù erekúṣu sì sálọ, a kò sì ri àwọn òkè ńlá mọ́ Yìnyín ńlá, tí ọkọkan rẹ̀ tó talẹ́ntì ní ìwọ̀n, sì bọ́ lù àwọn ènìyàn láti ọ̀run wà Àwọn ènìyàn sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu yìnyín náà nítorí tí ìyọnu rẹ̀ náà pọ̀ gidigidi Obìnrin Àti Ẹranko Ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì méje náà tí ó ní ìgò méje wọ̀n-ọn-nì sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, Wá níhìn-ín èmi ó sì fi ìdájọ́ àgbèrè ńlá ní tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ han ọ Ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe àgbèrè, tí a sì fi ọtí wáìnì àgbèrè rẹ̀ pá àwọn tí ń gbé inú ayé Ó sì gbé mi nínú ẹ̀mí lọ sí ihà mo sì rí obìnrin kan ó jòkòó lórí ẹranko aláwọ̀ òdòdó kan tí ó kún fún orúkọ ọ̀rọ̀ òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ odòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti pérílì ṣe é lọ́sọ̀ọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbérè rẹ̀ Àti níwájú rẹ̀ ni orúkọ kan tí a kọ OHUN ÌJÌNLẸ̀ BÁBÍLÓNÌ ŃLÁ ÌYÁ ÀWỌN PANṢÁGÀ ÀTI ÀWỌN OHUN ÌRÍRA AYÉ Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jésù ní àmuyó Nígbà tí mo sì rí i, ẹnu yà mi gidigidi Ańgẹ́lì sì wí fún mi pé, Nítorí kí ni ẹnu ṣe yà ọ́ Èmi ó sọ ti ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ, àti ti ẹranko tí ó gùn, ti ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá Ẹranko tí ìwọ ri nì, o ti wà, kò sì sí mọ́ Yóò sì ti inú ọ̀gbun gòkè wá, yóò sì lọ sínú ìwé iye láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nígbà tí wọn ń wò ẹranko tí o ti wà, tí kò sì sí mọ́, tí ó sì ń bọ̀ wá Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó Ọba méje sì ní wọn àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkurú Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì sí, òun náà sì ni ìkẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun Ìwo mẹ́wáà tí ìwọ sì rí ni ọba mẹ́wàá ni wọn, tí wọn kò ì ti gba ìjọba ṣùgbọ́n wọn gba ọlá bí ọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan Àwọn wọ̀nyí ní inú kan, wọ́n ò sì fi agbára àti ọlá wọn fún ẹranko náà Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti Ọba àwọn ọba Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtọ́ yóò sì sẹ́gun pẹ̀lú Ó sì wí fún mi pé, Àwọn omi tí ìwọ ti rí ni, níbi tí àgbèrè náà jókòó, àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti orílẹ̀ àti oníruru èdè ni wọ́n Àti ìwo mẹ́wàá tí ìwọ rí, àti ẹranko náà, àwọn wọ̀nyí ni yóò koríra àgbèrè náà, wọn ó sì sọ ọ́ di ahoro àti ẹni ìhòòhò, wọn ó sì jẹ ẹran ara rẹ̀, wọn ó sì fi iná sun ún pátapáta Nítorí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn wọn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, láti ní inú kan, àti láti fi ìjọba wọn fún ẹranko náà, títí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi ṣẹ Obìnrin tí ìwọ rí ní ìlú ńlá ni, tí ń jọba lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé Ìṣubú Bábílónì Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn, ó ń ti ọ̀run sọkalẹ̀ wá ti òun ti agbára ńlá ilẹ̀ ayé sì ti ipa ògo rẹ̀ mọ́lẹ̀ Ó sì kígbe ní ohùn rara, wí pé Bábílónì ńlá ṣubú! Ó ṣubú! Ó sì di ibùjókòó àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù, àti ihò ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo, àti ilé ẹyẹ àìmọ́ gbogbo, àti ti ẹyẹ ìríra Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè, àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀ Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ẹ ma bàá ṣe alábàápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ẹ ma bàá si ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀ Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti rántí àìsedédé rẹ̀ San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní, kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ Nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì Níwọ̀n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó, tí ó sì hùwà wọ̀bìà, níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́ nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé, Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé Nítorí náà, ní ìjọ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé, ìkú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn a ó sì fi iná sun ún pátapáta nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀ Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbérè, ti wọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀ Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé  Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, Bábílónì ìlú alágbára nì! Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé! Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń sọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́ Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti pẹ́rílì, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti sẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabílì Àti ti Kínamónì, àti ti onírúurú ohun olóòórun dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti oróro, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti àlìkámà, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹ̀sin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe Ìfẹ́kufẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè rére nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ oró rẹ̀, wọn o máa sọ́kún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀, Wí pé  Ẹ̀gbẹ́! Ẹ̀gbé, ni fún ìlú ńlá nì, tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe lọ́sọ̀ọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti pẹrílì! Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán! Àti olúkulùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ìbikíbí, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú òkun dúró ní òkèrè réré, Wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé  Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀ ní òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀! Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run! Àti ẹ̀yin Àpósítélì mímọ́ àti wòlíì! Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀   Ańgẹ́lì alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú òkun, wí pé Báyìí ní a ó fi agbára ńlá bíi Bábílónì ìlú ńlá ni wó, a kì yóò sì rí i mọ́ láé Àti ohùn àwọn aludùùrù, àti ti àwọn olórin, àti ti àwọn afọnrèrè, àti ti àwọn afọ̀npè, ni a kì yóò sì gbọ́ nínú rẹ mọ́ rara àti olukulùkù oníṣọ̀nà ohunkóhun ni a kì yóò sì rí nínú rẹ mọ́ láé Àti ìró ọlọ ní a kì yóò sì gbọ́ mọ̀ nínú rẹ láé Àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà ni kì yóò sì tàn nínú rẹ̀ mọ́ láé a kì yóò sì gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé nítorí pé àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni àwọn ẹni ńlá ayé nítorí pé nípa ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ní a fi tàn orílẹ̀ èdè gbogbo jẹ Àti nínú rẹ̀ ní a gbé ri ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì, àti ti àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé Halelúyà Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé Halelúyà! Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá agbára, nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀ Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì, tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ́ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà Àti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé Halelúyà! Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé Àmín, Halelúyà! Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé Ẹ máa yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo, ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti èwe àti àgbà! Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé Halelúyà! Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jọba Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi, kí a sì fi ògo fún un Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé, aya rẹ̀ sì ti múra tán Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́ tí ó funfun gbòò Ó sì wí fún mi pé, Kọ̀wé rẹ̀, Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè-alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn   Ó sì wí fún mi pé Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un Ó sì wí fún mi pé, Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀ ìránṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jésù mú foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run nítorí pé ẹ̀rí Jésù ni ìsọtẹ́lẹ̀ Mo sì rí ọ̀run sí sílẹ̀, sì wò ó, ẹsin funfun kan ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòótọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkárarẹ̀ A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọrùn tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ̀yìn lórí ẹ̀sin funfun Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi ṣá àwọn orílẹ̀-èdè Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ ỌBA ÀWỌN ỌBA ÀTI Olúwa ÀWỌN Olúwa Mo sì rí ańgẹ́lì kan dúró nínú òòrùn ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè-ńlá Ọlọ́run Kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹsin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrù, àti ti èwe àti ti àgbà Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbájọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹsin náà àti ogun rẹ̀ jagun A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba àmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ Àwọn méjèèje yìí ni a sọ láàyè sínú adágún iná tí ń fi súfúrù jó Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹsin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde Gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran ara wọn yó Sí Ìjọ Éfésù Sí Ańgẹ́lì Ní Éfésù kọ̀wé Nǹkan wọ̀nyí ní ẹni tí ó mú ìràwọ̀ méje náà ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ẹni tí ń rìn ní àárin ọ̀pá wúrà fìtílà méje Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní àpósítélì, tí wọ́n kì í sì í se bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọjú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ Ṣíbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹsílẹ̀ Rántí ibi tí ìwọ ti gbé subú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìsáájú bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì sí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikoláétánì, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mi ń sọ fún àwọn ìjọ Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìye nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrin Párádísè Ọlọ́run Àti sí Ańgẹ́lì Ìjọ ní Símírínà Kọ̀wé Nǹkan wọ̀nyí ni ẹni tí í ṣe ẹni-ìṣáájú àti ẹni-ìkẹyìn wí, ẹni tí ó ti kú, tí ó sì tún yè Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́ èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé Júù ni àwọn tìkárawọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ sínágọ́gù ti Sátánì Máṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀ Kíyèsí i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túúbú, kí a lè dán yin wò ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá ìwọ sa se olóòtọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ Ẹni tí ó bá sẹ́gun kì yóò farapa nínú ikú kejì Àti sì Ańgẹ́lì ìjọ ni Págámọ́sì Kọ̀wé Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ní ídà mímú olójú méjì, Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Sàtánì wà Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Áńtípà ẹlẹ́rì mi, olóòótọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrin yín, níbi tí Sàtánì ń gbé Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí o di ẹ̀kọ́ Báláámù mú nibẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Bálákì láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá ṣíwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ní àwọn tí ó gbá ẹ̀kọ́ àwọn Nikoláétanì pẹ̀lú, ohun tí mo kórìíra Nítorí náàonúpìwàdà bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó tọ̀ ọ́ wá nísinsinyìí, èmí o sì fi idà ẹnu mi bá wọn jà Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi mánà tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á Àti sí Ańgẹ́lì ìjọ ní Tíátírà kọ̀wé Nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀ àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí iṣàájú lọ Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sì ọ Nítorí tí ìwọ fi àyè sílẹ̀ fún obìnrin Jésébẹ́lì tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì Nípaṣ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sì òrìṣà Èmi fi àkókò fún un, láti ronúpìwàdà ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ ronúpìwàdà àgbèrè rẹ̀ Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn Èmi o pa àwọn ọmọ rẹ̀ gbogbo ìjọ ni yóò sì mọ̀ pé, èmi ni ẹni tí ń wádìí inú àti ọkàn èmi ó sì fi fún olúkúlùkù yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni mò ń sọ fún, ẹ̀yin ìyókù tí ń bẹ ní Tíátírà, gbogbo ẹ̀yin tí kò ni ẹ̀kọ́ yìí, ti kò ì tí ì mọ̀ ohun tí wọn pe ni ohun ìjìnlẹ̀ Sàtánì, èmi kò di ẹrù mìíràn rù yín Ṣùgbọ́n èyí tí ẹ̀yin ní, ẹ di i mú ṣinṣin títí èmi ó fi dé Ẹni tí ó bá sì ṣẹ́gun, àti tí o sì ṣe ìfẹ́ mi títí dé òpin, èmi o fún un láṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn gẹ́gẹ́ bí a ti ń fọ́ ohun-èlò amọ̀kòkò ni a ó fọ́ wọn túútúú, gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tí gbà àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi Èmi yóò sì fi ìràwọ̀ òwúrọ̀ fún un Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ Ìjọba Ẹgbẹ̀rún Ọdún Mo sì rí ańgẹ́lì kan ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ti òun ti kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbún, àti àwọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀ O sì di Dírágónì náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Sàtánì, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún ọdún Ó sì gbé e sọ sínú ọ̀gbún náà, ó sì tì í, ó sì fi èdìdì dì í lórí rẹ̀, kí ó má ba à tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé Lẹ́yìn èyí, a kò le sàì tú u sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọn mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jésù, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà àmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn wọ́n sì wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹ̀lú Kírísítì ní ẹgbẹ̀rún ọdún Àwọn òkú ìyókù kò wà láàyè mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé Èyí ni àjíǹde èkíní Olúkúlùkù àti mímọ́ ni ẹni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkíní náà lórí àwọn wọ̀nyí ikú eekejì kò ní agbára, ṣùgbọ́n wọn ó jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kírísítì, wọn ó sì máa jọba pẹ̀lú rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọdún Nígbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá sì pé, a ó tú Sàtánì sílẹ̀ kúrò nínú túbú rẹ̀ Yóò sì jáde lọ láti máa tan àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé jẹ, Gógù àti Mágógú, láti gbá wọn jọ sí ogun àwọn tí iyè wọn dàbí iyanrìn òkun Wọ́n sì gòkè lọ la ibú ayé já, wọ́n sì yí ibùdó àwọn ènìyàn mímọ́ ká àti ìlú àyànfẹ́ náà iná sì ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó sì jó wọn run A sì wọ́ Èsù tí ó tàn wọ́n jẹ lọ sínú adágún iná àti súfúrù, níbi tí ẹranko àti wòlíì èké nì gbé wà, a ó sì máa dá wọn lóró tọ̀sán tòru láé àti láéláé Mo sì rí ìtẹ́ funfun ńlá kan, àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, níwájú ẹni tí ayé àti ọ̀run fò lọ a kò sì rí àyè fún wọn mọ́ Mo sì rí àwọn òkú, àti èwe àti àgbà, wọn dúró níwájú ìtẹ́ a sì sí àwọn ìwé sílẹ̀ a sì ṣí àwọn ìwé mìíràn kan sílẹ̀ tí í ṣe ìwé ìyè a sì ṣe ìdájọ́ fún àwọn òkú láti inú ohun tí a ti kọ sínú àwọn ìwé náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́ àti òkú àti ipò-òkú sì jọ̀wọ́ òkú tí ó wà nínú wọn pẹ̀lú a sì ṣe ìdájọ́ wọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn Àti ikú àti ipò-òkú ni a sì sọ sínú adágún iná Èyí ni ikú kejì Bí a bá sì rí ẹnikẹ́ni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè, a ó sọ ọ́ sínú adágún iná Jerúsálémù Tuntun Mo sì rí ọ̀run titun kan àti ayé titun kan nítorí pé ọ̀run ti ìṣáajú àti ayé ìṣáajú ti kọjá lọ òkun kò sì sí mọ́ Mo sì rí ìlú mímọ́, Jerúsálémù titun ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a ti múra sílẹ̀ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀ Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkararẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn kì yóò sì sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́ nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun! Ó sì wí fún mi pé, Kọ̀wé rẹ̀ Nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n Ó sì wí fún mi pé, Ó parí Èmi ni Álfà àti Ómégà, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí oúngbẹ ń gbẹ láti orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́ Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fí iná àti súfúrù jó èyí tí i ṣe ikú kéjì Ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì méje, tí wọ́n ni ìgò méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, Wá níhìnín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-Àgùntàn hàn ọ́ Ó sì mu mi lọ nínú Ẹ̀mí si òkè ńlá kan tí o sì ga, ó sì fí ìlú náà hàn mi, Jerúsálémù mímọ́, tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Tí ó ní ògo Ọlọ́run ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sì dàbí òkúta iyebíye gidigidi, àní bí òkúta Jasípérì, ó mọ́ bí Kírísítálì Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu-bodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu-bodè náà áńgẹ́lì méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Ní ìhá ìlà-oòrùn ẹnu-bodè mẹ́ta ní ìhà àríwá ẹnu-bodè mẹ́ta ní ìhà gúsù ẹnu-bodè mẹ́ta àti ní ìhà ìwọ̀-òòrùn ẹnu-bodè mẹ́ta Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Àpósítélì méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn Ẹni tí o sì ń bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pá-ìwọ̀n wúrà kan láti fi wọn ìlú náà àti àwọn ẹnu-bodè rẹ̀, àti odi rẹ̀ Ìlú náà sì wà ní ibú mẹ́rin lọ́gbọọgba, gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀ sì dọ́gba ó sì fi ọ̀pá-ìwọ̀n náà wọn ìlú náà wò, ó jẹ ẹgbàafà ibùsọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀, àti gíga rẹ̀ sì dọ́gba Ó sì wọn odi rẹ̀ ó jẹ̀ ogóje ìgbọ̀nwọ́ lé mẹ́rin , gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni tí ańgẹ́lì náà A sì fi Jásípérì mọ odi ìlú náà Ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí tí o mọ́ kedere A fi onírúuru òkúta iyebíye ṣe ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́ Ìpìlẹ̀ ìkínní jẹ́ jásípérì ìkejì, sáfírù ìkẹta, kalíkedónì ìkẹrin, emeralídì Ikarun, sadonikísì ìkẹfà, kanelíánì ìkeje, kírisolítì ìkẹjọ bérílì ìkẹsan, tọ́pásì ìkẹwàá, kírísopírasù ìkọkànlá, jakinítì ìkejìlá, ámétísítì Ẹnu-bodè méjèèjìlá jẹ́ pẹ́rílì méjìlá olúkúlùkù ẹnu-bodè jẹ́ pérílì kan ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán Èmi kò sì ri tẹḿpílì nínú rẹ̀ nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni téḿpílì rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-Àgùntàn Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀ Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀ A kì yóò sì ṣé àwọn ẹnu-bodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán nítorí ki yóò si òru níbẹ̀ Wọ́n ó sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀ Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn Omi Ìyè Ó sì fi odò omi ìyè kan hàn mi, tí ó mọ́ bí Kírísítalì, tí ń tí ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn jáde wá, Ní àárin ìgboro rẹ̀, àti níhà ìkínní kéjì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so oníruurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà Ègún kì yóò sì sí mọ ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni yóò sì máa wà níbẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì máa sìn ín Wọ́n ó si máa rí ojú rẹ̀ orúkọ rẹ̀ yóò si máa wà ni ìwájú orí wọn Òru kì yóò sí mọ́ wọn kò sì ní wa ìmọ́lè fìtílà, tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn nítorí pé Olúwa Ọlọ́run ni yóò tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn wọn ó sì máa jọba láé àti láéláé Ó sì wí fún mi pé, Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran ańgẹ́lì rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ Kíyèsí i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́! Èmi, Jòhánù, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ ańgẹ́lì náà, tí o fí nǹkan wọ̀nyí hàn mi, Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀ ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́ foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run! Ó sì wí fún mi pé, Má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀ Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì ṣó Àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nìṣó Àti ẹni tí ń ṣe olòdodo, kí ó máa ṣe òdodo nìṣó Àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nìṣó Kíyèsí i, èmi ń bọ̀ kánkán èrè mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, láti sán fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ yóò tí rí Èmi ni Álífà àti Òmégà, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni àǹfààní láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu-bodè wọ inú ìlú náà Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbérè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké Èmi, Jésù, ni ó rán ańgẹ́lì mi láti jẹ̀rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ Èmi ni gbòngbò àti irú-ọmọ Dáfídì, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, Máa bọ! Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, Máa bọ̀! Àti ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́ Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkú ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fí kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un Bí ẹnikẹ́ni bá sì mú kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò sì mú ipa tirẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, àti kúró nínu ìlú mímọ́ náà, àti kúrò nínú àwọn ohun tí a kọ sínú ìwé yìí Ẹni tí ó jẹ̀rìí nǹkan wọ̀nyí wí pé, Nítòótọ́ èmi ń bọ̀ kánkán Àmín, Má a bọ̀, Jésù Olúwa! Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn-mímọ́ Àmín Sí Ìjọ Ní Sádísì Àti sí Ańgẹ́lì ìjọ ni Sádísì kọ̀wé Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ni Ẹ̀mí méje Ọlọ́run, àti ìràwọ̀ méje wí pé Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ̀, àti pé ìwọ ni orúkọ pé ìwọ ń bẹ láàyè, ṣùgbọ́n ìwọ ti kú Jí, kí o sì fi ẹsẹ̀ ohun tí ó kù múlẹ̀, tí ó ṣetán láti kú Nítorí èmi kò rí iṣẹ́ rẹ ni pípé níwájú Ọlọ́run Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ Ìwọ ní orúkọ díẹ̀ ní Sádísì, tí kò fi aṣọ wọn yí èérí wọn yóò sì máa ba mi rìn ní aṣọ funfun nítorí wọ́n yẹ Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀ èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ Ẹni tí ó ba létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń ṣọ fún àwọn ìjọ Àti sí Ańgẹ́lì Ìjọ ni Filadéfíà Kọ̀wé Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ náà wí, ẹni tí ó ṣe olóòótọ́, ẹni tí ó ní kọ́kọ́rọ́ Dáfídì, ẹni tí ó sí, tí kò sí ẹni tí yóò tì ẹni tí o sì tì, tí kò sì ẹni tí yóò ṣí i Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀ kíyèsí i, mo gbe ilẹ̀kùn tí ó ṣí kálẹ̀ níwájú rẹ̀, tí kò sí ẹni tí o lè tì í pé ìwọ ni agbára díẹ̀, ìwọ sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, ìwọ kò sì sẹ́ orúkọ mi Kíyèsí i, èmi ó mú àwọn ti sínágógù Sàtánì, àwọn tí wọ́n ń wí pé Júù ni àwọn, tí wọn kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọn ń ṣèké kíyèsí i, èmi ó mú kí wọn wá wólẹ̀ níwájú ẹṣẹ̀ rẹ̀, kí wọn sì mọ̀ pé èmi tí fẹ́ ọ Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò Kíyèsí i, èmi ń bọ̀ kánkán di èyí ti ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́ èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerúsálémù tuntun, tí ó ń ti ọrun sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá àti orúkọ tuntun ti èmi tikarámì Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun ti Ẹmi ń sọ fún àwọn ìjọ Àti sí áńgẹ́lì ìjọ ní Láódékíá kọ̀wé Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòótọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ kò gbóná bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò tútù èmi ìbá fẹ́ pé kí ìwọ kúkú tutù, tàbí kí ìwọ kúkú gbóná Ǹjẹ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi Nítorí tí ìwọ wí pé, Èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò si ṣe aláìní ohunkóhun tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ikáànù, tálákà, afọ́jú, àti ẹni-ìhòhò Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀ àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran Gbogbo àwọn ti èmi bá fẹ́ ni èmi ń bá wí, tí mo sì ń nà nítorí náà, ní ìtara, kì ìwọ sì ronúpìwàdà Kíyèsí i, èmi dúró ni ẹnu ilẹ̀kùn, èmi sì ń kànkùn, bí ẹnikẹ́ni bá gbọ ohun mi, tí ó sì ṣí ilẹ̀kùn, èmi yóò sì wọlé tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bá a jẹun, àti òun pẹ̀lú mi Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi fún láti jókòó pẹ̀lu mi lórí ìtẹ́ mi, bí èmi pẹ̀lú ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀ Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń ṣọ fún àwọn Ìjọ Ìtẹ́ Ọ̀run Lẹ́yin nǹkan wọ̀nyí èmi wò, sì kíyèsí i, ìlẹ̀kùn kan ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run Ohùn kìn-ín-ní tí mo gbọ́ bí ohùn ìpè tí ń bá mi sọ̀rọ̀, tí ó wí pé, Gòkè wá níhìn-ín, èmi ó sì fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ̀yìn èyí hàn ọ́ Lójú kan náà, mo sì wà nínú Ẹ̀mí sì kíyèsí i, a tẹ́ ìtẹ́ kan lọ́run ẹnìkan sì jókòó lórí ìtẹ́ náà Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jásípérì àti sádíúsì lójú Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta émérádì lójú Yíká ìtẹ́ náà sì ni ìtẹ́ mẹ́rínlélógún àti lórí àwọn ìtẹ́ náà mo rí àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún jókòó, tí a wọ̀ ni aṣọ àlà adé wúrà sì wà ni orí wọn Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni ìró mọ̀nàmọ́ná àti ohùn àti àrá ti jáde wá níwájú ìtẹ́ náà ni fìtílà iná méje sì ń tàn, èyí tí ń ṣe Ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni òkun bi digi wà tí o dàbí Kírísítálì Àti yí ìtẹ́ náà ká ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí ó kún fún ojú níwájú àti lẹ̀yìn wà Ẹ̀dá kínní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kéjì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹ́rin sì dàbí ìdì tí ń fò Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú wọn kò sì sinmi lọ́sàn-ań àti lóru, láti wí pé Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́, Olúwa Ọlọ́run Olódùmare, tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá! Nígbà tí àwọn ẹ̀dá aláàyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láàyè láé àti láéláé Àwọn àgbà mẹ́rinlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé Olúwa, ìwọ ni o yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni wọn fi wà tí a sì dá wọn Ìwé Àti Ọ̀dọ́ Agùntàn Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ̀yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí Mó sì rí ańgẹ́lì alágbára kan, ó ń fi ohùn rara kéde pé, Táni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, àti láti tu èdìdì rẹ̀ Kò sì sí ẹni kan ní ọ̀run, tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀, tí ó le ṣí ìwé náà, tàbí ti o lè wo inú rẹ̀ Èmi sì sọkùn gidigidi, nítorí tí a kò ri ẹnìkan tí o yẹ láti sí i àti láti ka ìwé náà, tàbí láti wo inú rẹ̀ Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, Má ṣe sọkún kíyèsí i, kìnnìún ẹ̀yà Júdà, Gbòǹgbò Dáfídì, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje Mo sì rí i ni àárin ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárin àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-Àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mi méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo Ó sì wá, o sì gbà á ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú háàpù kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́ Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà, àti láti ṣí èdìdì rẹ̀ nítorí tí a tí pa ọ, ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo, àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá Ìwọ sì tí ṣe wọ́n ni ọba àti àlùfáà sì Ọlọ́run wá wọ́n sì ń jọba lórí ilẹ̀ ayé Èmi sì wò, mo sì gbọ́ ohùn àwọn ańgẹ́lì púpọ̀ yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn ẹ̀dá alààyè náà àti àwọn àgbà náà ká Iye wọn sì jẹ́ ẹgbàárun ọ̀nà ẹgbàarún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún Wọn ń wí lóhùn rara pé Yíyẹ ni Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà tí a tí pa, láti gba agbára, àti ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n, àti ipá, àti ọlá, àti ògo, àti ìbùkún Gbogbo ẹ̀dá tí o sì ń bẹ ni ọ̀run, àti lórí ilẹ̀ ayé, àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ àti irú àwọn tí ń bẹ nínú òkun, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé, Kí a fi ìbùkún àti ọlá, àti ògo, àti agbára, fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà láé àti láéláé Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé, Àmín! Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé Àwọn Èdìdì Ìwé Náà Èmi sì rí i nígbà tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà sí ọkàn nínú èdìdì wọ̀nyí, mo sì gbọ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń wí bí sísán àrá pé, Wá, wò ó! Mo sì wò ó, kíyèsí i, Ẹṣin funfun kan ẹni tí ó sì jókòó lórí i rẹ̀ ní ọrùn kan a sì fi adé kan fún un ó sì jáde lọ láti ìṣẹ́gun dé ìsẹ́gun Nígbà tí ó sì sí èdìdì kéjì, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè wí pé, Wá, wò ó! Ẹṣin mìíràn tí ó pupa sì jáde a sì fi agbára fún ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, láti gba àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àti pé kí wọn kí ó máa pa ara wọn A sì fi idà ńlá kan lé e lọ́wọ́ Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹ́tà, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, Wá, wò ó Mo sì wò ó, sì kíyèsí i, ẹṣin dúdú kan ẹni tí ó jókòó lórí ni ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀ Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárin àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òsùwọ̀n àlìkámà kan fún owó idẹ kan, àti òṣùwọ̀n ọkà-bálì mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsí i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹ́rin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, Wá wò ó Mo sì wò ó, kíyèsi, ẹ̀ṣin ràndànràndàn kan orúkọ ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni ikú, àti ipò òkú sì tọ̀ ọ́ lẹ̀yìn A sì fi agbára fún wọn lórí ìdá mẹ́rin ayé, láti fi idà, àti ebi, àti ikú, àti ẹranko lu orí ilẹ̀ ayé pa Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìmú Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, ẹ̀mí mímọ́ àti olóòótọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí ó ti pa bí wọn, yóò fi dé Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfa mo sì rí i, sì kíyèsí i, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀ ọ̀run sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òsùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀ Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùsù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olókúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè Wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà Nítorí ọjọ́ ńlá ìbínú wọn dé ta ni sì le dúró Ọ̀kẹ́ Méje-Ólé-Ẹgbàá-Méjì Èdìdí Ìwé Lẹ́yìn èyí ni mo rí ańgẹ́lì mẹ́rin dúró ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú, kí ó má ṣe fẹ́ sórí ilẹ̀, tàbí sórí òkun, tàbí sára igikígi Mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-òòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́ ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn ańgẹ́lì mẹ́rin náà tí a fifún un láti pa ayé, àti òkun, lára, Wí pé, Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si Àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje o lé ẹgbàájì láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá Láti inú ẹ̀yà Júdà a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà Láti inú ẹ̀yà Reubẹ́nì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà Láti inú ẹ̀yà Gádì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà Láti inú ẹ̀yà Ásérì a fi èdídí sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà Láti inú ẹ̀yà Nefítalímù a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà Láti inú ẹ̀yà Mánásè a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà Láti inú ẹ̀yà Simeónì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà Láti inú ẹ̀yà Léfì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà Láti inú ẹ̀yà Ísakárì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà Láti inú ẹ̀yà Sebulúnì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà Láti inú ẹ̀yà Jósẹ́fù a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà Láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsí i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn Wọn sì kígbe ni ohùnrara, wí pé Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wá tí o jókòó lórí ìtẹ́, àti ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn! Gbogbo àwọn ańgẹ́lì sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run Wí pe Àmín! Ìbùkún, àti ògo, àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá, àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé! Àmín! Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun Níbo ni wọn sì ti wá Mo sì wí fún un pé, Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀ Ó sì wí fún mí pé, Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú Ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà Nítorí náà ni, wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹḿpílì rẹ̀ ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si ṣíji bò wọn Ebi kì yóò pa wọn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òungbẹ kì yóò gbẹ́ wọ́n mọ́ bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọn tàbí oorukóoru kan Nítorí òdọ̀-Àgùntàn tí ń bẹ ni àárin ìtẹ́ náà ni yóò máa ṣe Olùṣọ́-Àgùntàn wọn, tí yóò sì máa ṣe amọ̀nà wọn sí ibi orísun omi ìyè Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn Èdìdì Kéje Àti Àwo Tùràrí Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kéje, ìdákẹ́ rọ́rọ́ sì wà ní ọ̀run níwọ́n ààbọ̀ wákàtí kan Mo sì rí àwọn ańgẹ́lì méje tí wọn dúró níwájú Ọlọ́run a sì fi ìpè méje fún wọn Ańgẹ́lì mìíràn sì wá, ó sì dúró ti pẹpẹ, ó ní àwo tùràrí wúrà kan a sì fi tùràrí púpọ̀ fún un, láti máa fí kún àdúrà gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ lórí pẹpẹ, pẹpẹ wúrà tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ Àti èéfín tùràrí náà pẹ̀lú àdúrà àwọn ènìyàn-mímọ́ sì gòkè lọ ṣíwájú Ọlọ́run láti ọwọ́ ańgẹ́lì náà wá Ańgẹ́lì náà sì mú àwo tùràrí náà, ó sì fi iná orí pẹpẹ kùn ún, ó sì dà á sórí ilẹ̀ ayé A sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, mọ̀nàmọ́ná sì kọ, àti ilẹ̀-rírì Àwọn ańgẹ́lì méje náà tí wọn ni ìpè méje sì múra láti fún wọn Èkínní sì fọn ìpè tirẹ̀ Yìnyín àti iná, tí o dàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, sì jáde, a sì dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé ìdámẹ̀ta ilẹ̀ ayé si jóná, ìdámẹ̀ta àwọn igi sì jóná, àti gbogbo koríko tútù sì jónà Ańgẹ́lì kéjì si fún ìpè tirẹ̀, a sì sọ ohun kan, bí òké-ńlá tí ń jóná, sínú òkun ìdámẹ̀ta òkun si di ẹ̀jẹ̀ Àti ìdámẹ̀ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú òkun tí ó ni ẹ̀mí sì kú àti ìdámẹ̀ta àwọn ọkọ̀ si bàjẹ́ Ańgẹ́lì kẹ́ta sì fún ìpè tirẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ń jó bí fìtílà sì bọ́ láti ọ̀run wá, ó sì bọ́ sórí ìdámẹ̀ta àwọn odò ṣíṣàn, àti sórí àwọn orísun omi A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ni ìwọ̀, ìdámẹ̀ta àwọn omi sì di ìwọ̀, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn sì tí ipa àwọn omi náà kú, nítorí tí a sọ wọn di kíkorò Ańgẹ́lì kẹ́rin sì fún ìpè tirẹ̀, a sì kọlu ìdámẹ̀ta òòrùn, àti ìdámẹ̀ta òṣùpá, àti ìdámẹ̀ta àwọn ìràwọ̀, ki ìdámẹ̀ta wọn lè ṣóòkùn, kí ọjọ́ má ṣe mọ́lẹ̀ fún ìdámẹ̀ta rẹ̀, àti òru báka náà Mo sì wò, mo sì gbọ́ idí kan tí ń fò ni àárin ọ̀run, ó ń wí lóhùn rara pé, Ègbé, ègbé, fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé nítorí ohun ìpè ìyókù tí àwọn ańgẹ́lì mẹ́ta tí ń bọ̀ wá yóò fún! Ańgẹ́lì karùn-ún sì fún ìpè tirẹ̀ mo sì rí ìràwọ̀ kan bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run wá a sì fi kọ́kọ́rọ́ ihò ọ̀gbun fún un Ó sì sí ihò ọ̀gbun náà, èéfín sì rú jáde láti inú ihò náà wá, bí èèfín ìléru ńlá, òòrùn àti ojú sánmà sì ṣóòkùn nítorí èéfín ihò náà Àwọn eṣú sì jáde ti inú èéfín náà wá sórí ilẹ̀ a sì fi agbára fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbára àkéekèe ilẹ̀ A sì fún wọn pé ki wọn má ṣe pa koríko ilẹ̀ lára tàbí ohun tútù kan, tàbí igikígi kan bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí kò ni èdìdì Ọlọ́run ní iwájú wọn A sì pàṣẹ fún wọn pé, kí wọn má ṣe pa wọ́n, ṣùgbọ́n kí a dá wọn ni oró ni oṣù marùn-ún oró wọn sì dàbí oró àkéekèe, nígbà tí o bá ta ènìyàn Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn yóò sì máa wá ikú, wọn kì yóò sì rí i wọn yóò sì fẹ́ láti kú, ikú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn Ìrísí àwọn eṣú náà sì dàbí àwọn ẹṣin tí a múra sílẹ̀ fún ogun àti ní orí wọn ni ohun tí o dàbí àwọn adé wúrà wà, ojú wọn sì dàbí ojú ènìyàn Wọn sì ní irun bí obìnrin, ehín wọn sì dàbí ti kìnìún Wọn sì ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin ìró ìyẹ́ wọn sì dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ẹsin púpọ̀ tí ń súré lọ sí ogun Wọ́n sì ni ìrù àti oró bí tí àkéekèe, àti ní ìrù wọn ni agbára wọn wà láti pa ènìyàn lára fún oṣù márùn-ún Wọ́n ní ańgẹ́lì ọ̀gbun náà bí ọba lórí wọn, orúkọ rẹ̀ ní èdè Hébérù ní Ábádónì, àti ni èdè Gíríkì orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Àpólíónì Ègbé kan tí kọjá, kíyèsi i, ègbé méjì ń bọ̀ síbẹ̀ lẹ́yìn èyí Ańgẹ́lì kẹ́fà si fún, mo sì gbọ́ ohùn kan láti ibi ìwo mẹ́rin pẹpẹ wúrà wá, tí ń bẹ níwájú Ọlọ́run Òun wí fún ańgẹ́lì kẹ́fà náà tí o ni ìpè náà pé, Tú àwọn ańgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀ tí a dè lẹ́bàá odò ńlá Yúfúrátè! A sì tú àwọn ańgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀, tí a ti pèṣè tẹ́lẹ̀ fún wákàtí náà, àti ọjọ́ náà, àtí oṣù náà, àti ọdún náà, láti pa ìdámẹ̀ta ènìyàn Iye ogún àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà igba mo sì gbọ́ iye wọn Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jàkìntì, àti tí súfúrù orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìninún àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti súfúrù tí ń jáde Nípa ìyọnu mẹ́ta wọ̀nyí ni a tí pa ìdámẹ̀ta ènìyàn, nípa iná, àti nípa èéfín, àti nípa súfúrù tí o ń tí ẹnu wọn jáde Nítorí pé agbára àwọn ẹṣin náà ń bẹ ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn Nítorí pé ìrù wọn dàbí ejò, wọn sì ní orí, àwọn wọ̀nyí ni wọn sì fi ń pani lára Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìyókù tí a kò sì ti ipa ìyọnu wọ̀nyí pa, kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọn má ṣe fàdákà, àti ti idẹ, àti òkúta, àti ti igi mọ́ àwọn tí kò lè ríran, tàbí kí wọn gbọ́ràn, tàbí kí wọn rìn Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ronúpìwàdà ìwà ìpànìyàn wọn, tàbí oṣó wọn tàbí àgbérè wọn, tàbí olè wọn Ọ̀rọ̀ Ìkíni Pọ́ọ̀lù Sí Àwọn Àyànfẹ́ Pọ́ọ̀lù, ìránṣẹ́ Jésù Kírísítì ẹni tí a ti pè láti jẹ́ Àpósítélì, tí a sì ti yà sọ́tọ̀ láti wàásù ìyìnrere Ọlọ́run Ìyìnrere tí a ti pinnu láti ẹnu àwọn wòlíì nínú ìwé Mímọ́ láti ìgbà pípẹ́ ṣáájú ìsinsin yìí Nípa ìfiyèsí ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ ìran Dáfídì nípa ìbí ti ènìyàn Ẹni tí a pinnu rẹ̀ láti jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ẹmi ìwà mímọ́, nípa àjíǹde kúrò nínú òkú, àní Jésù Kírísítì Olúwa wa Láti ọdọ ẹni tí àwa rí oore-ọ̀fẹ́ àti jíjẹ́ Àpósítélì gbà, láti wàásù fún gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè kí wọn kí ó lè wá sínú ìgbàgbọ́ èyíni ní orúkọ rẹ̀ Ẹ̀yin pẹ̀lú si wa lára àwọn tí a pè sọ́dọ̀ Jésù Kírísítì Sí gbogbo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ní Róòmù tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́ Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa Jésù Kírísítì Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípaṣẹ̀ Jésù kírísítì fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé Ọlọ́run, ẹni tí èmí ń sìn tí mo sì fi gbogbo ọkàn mi jìn fún un láti máa wàásù ìyìnrere ọmọ rẹ̀, bí ó ti ṣe pé ní àìsinmi ni èmí ń rántí yín nígbà gbogbo nínú àdúrà mi nínú àdúrà mi ìgbà gbogbo mo tún ń gbàdúrà wí pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kí ọ̀nà ó sí fún mi láti wá sọ́dọ̀ yín Nítorí èmi ń fẹ́ gidigidi láti tọ̀ yín wá, kí èmi lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀, kí a bá a le sọ yín di alágbára nínú Olúwa, èyí nì ni pé, kí a lè jẹ́ ìwúrí fún ara wa nípa ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá, , kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrin yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní in láàrin àwọn aláìkọlà yóòkù Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Gíríkì àti sí àwọn ẹlòmíràn tí kì í se Gíríkì, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aláìgbọ́n Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Róòmù àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìyìn rere Ọlọ́run sí i yín Èmi kò tijú ìyìn rere Jésù, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún aláìkọlà pẹ̀lú Nítorí nínú ìyìnrere ni òdodo Ọlọ́rùn ti farahàn, òdodo Ọlọ́run láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀ bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáadáa, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ wọ́n ń rò èrò aṣiwèrè, ọkàn òmùgọ̀ wọn sì ṣókùnkùn Wọ́n Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kìí díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́ Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń forí balẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé Àmín Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́ ìwàkíwà nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ yí ìlò àdánidá padà sí èyí tí ó lòdì sí ti àdánidá Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìlò obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìsìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àránkan wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà-búburú wọ́n jẹ́ afi-ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-banijẹ́ Asọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, akóríra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọ́ràn sí òbí, Aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú Bí ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n Ẹ̀yin ará, ìfẹ́ ọkàn àti àdúrà mi ni pé, kí àwọn Júù rí ìgbàlà Mo mọ irú ìfẹ́ àti ìtara tí wọ́n ní sí ọlá àti ògo Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ọ̀nà ìsìnà ni wọn ń gbà wá Ọlọ́run Ìdí ni pé, wọ́n ń gbìyànjú láti hu ìwà rere nípa pípa òfin àti àṣà ìbílẹ̀ àwọn Júù mọ́, kí wọn báà lè rí ojú rere Ọlọ́run Kò yé wọn pé, Kírísítì ti kú láti mú wọn dọ́gba pẹ̀lú Ọlọ́run Òfin àwọn Júù àti àṣà ìbílẹ̀ wọn kì í ṣe ọ̀nà tí Ọlọ́run lè fi gba ènìyàn là Títí ìsinsin yìí, wọn kò ì tíì mọ̀ pé, Kírísítì kú láti pèsè ohun gbogbo tí wọ́n ń fi àníyàn wá kiri nípa òfin fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, ó ti fi òpin sí gbogbo rẹ̀ Nítorí pé Mósè kọ ọ́ pé, Kí ènìyàn tó lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìgbàlà gbà, ó ní láti ja àjàṣẹ́gun nínú gbogbo ìdánwò, kí ó sì wà láì dá ẹ̀ṣẹ̀ kan soso nínú gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ Ṣùgbọ́n ìgbàlà tí ó wà nípa ìgbàgbọ́ wí pé, A kò níláti lọ wá inú ọ̀run láti mú Kírísítì wá sí ayé kí ó bá à lè ràn wá lọ́wọ́ Bẹ́ẹ̀ ni, a kò níláti wọ ìsà òkú lọ láti jí Kírísítì dìde Nítorí pé, ìgbàlà tí ènìyàn ń ní nípa ìgbẹ́kẹ̀lé, nínú Kírísítì, ìgbàlà tí àwa ń wàásù rẹ̀, wà ní àrọ́wọ́tó ẹnikọ̀ọ̀kan wa Kódà, ó kínlẹ̀ sí wa tó bí ọkàn àti ẹnu wa ti kínlẹ̀ sí wa Nítorí pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Olúwa ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì jẹ́wọ́ rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn pé Jésù Kírísítì ní Olúwa rẹ, a ó gbà ọ́ là Nítorí pé, nípa ìgbàgbọ́ nínú ọkàn ni ènìyàn le gbà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run Bẹ́ẹ̀ ni ẹnu ni a sì fi ń sọ fún àwọn ẹlòmíràn ní ti ìgbàgbọ́ wa Nípa bẹ́ẹ̀, a sì sọ ìgbàlà wa di ohun tí ó dájú Nítorí pé, ìwé Mímọ́ sọ pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Kírísítì gbọ́ kò ní kábámọ̀ ojú kò ní ti olúwa rẹ̀ láéláé Òtítọ́ ni èyí pé, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́, ìbáà ṣe Júù tàbí aláìkọlà Ọlọ́run kan ni ó wà fún gbogbo wa, ó sì ń pín ọ̀rọ̀ rẹ̀ láì ní ìwọ̀n fún ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè rẹ̀ Ẹnikẹ́ni tí ó bá sà à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà Ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe le ké pé ẹni tí wọn kò gbàgbọ́ Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúró rẹ̀ rí gbọ́ Wọn o há sì ti ṣe gbọ́ láì sí oníwàásù Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìyìn rere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìhìn ìyìn àyọ̀ ohun rere! Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìyìn rere Nítorí Ìsáià wí pé, Olúwa, tali ó gba ìyìn wa gbọ́ Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́ Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀, àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ayé Ṣùgbọ́n mo wí pé, Ísírẹ́lì kò ha mọ̀ bí Mósè ni ó kọ́ wí pé, Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú Ṣùgbọ́n Ìsáià tilẹ̀ láyà, ó wí pé, Àwọn tí kò wá mi rí mi Àwọn tí kò béèrè mi ni a fi mí hàn fún Ṣùgbọ́n nípa ti Ísírẹ́lì ni ó wí pé, Ní gbogbo ọjọ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọn aláìgbọ́ràn àti aláríwísí ènìyàn Ìran aláìkọlà Pín Nínú ìgbàlà Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Ǹjẹ́ mo ní Ọlọ́run ha ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù bí Kí a má ri Nítorí Ísírẹ́lì ni èmi pẹ̀lú, láti inú irú-ọmọ Ábúráhámù, ni ẹ̀yà Béńjámínì Ọlọ́run kò ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù ti ó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ Tàbí ẹ̀yin kò mọ bí ìwé-mímọ́ ti wí ní ti Èlíjà Bí ó ti ń bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì, wí pé Olúwa, wọ́n ti pa àwọn wòlíì rẹ, wọn sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀ èmi nìkan soso ni ó sì kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi Ṣùgbọ́n ìdáhùn wo ni Ọlọ́run fi fún un Mo ti paẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin ènìyàn mọ́ sílẹ̀ fún ara mi, àwọn tí kò tẹ eékún ba fún Báálì ẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni li àkókò ìsinsin yìí pẹ̀lú, apákan wà nípa ìyànfẹ́ ti ore-ọ̀fẹ́ í ó bá sì ṣe pé nípa ti ore-ọ̀fẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti iṣẹ́ mọ́ àyàmọ̀bí ore-ọ̀fẹ́ kì í ṣe ore-ọ̀fẹ́ mọ́ Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pe nípa ti iṣẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti ore-ọ̀fẹ́ mọ́ àyàmọ̀bí iṣẹ́ kì í ṣe iṣẹ́ mọ́ Kí ha ni Ohun tí Isírẹ́lì ń wá kiri, òun náà ni kò rí ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìyànfẹ́ ti rí i, a sì ṣé àyà àwọn ìyókù le Èyí ni ìwé Mímọ́ ń wí nígbà tí ó sọ pé Ọlọ́run ti fi oorun kùn wọ́n, ó sì dí ojú àti etí wọn, wọn kò sì le ní ìmọ̀ Kírísítì nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ síwọn Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì rí títí di ọjọ́ òní Ohun kan náà yìí ni Dáfídì ọba sọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé Kí oúnjẹ àti àwọn nǹkan mèremère wọn tàn wọ́n, láti rò pé wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run Jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí padà dojú ìjà kọ wọ́n, kí a bá à lè fi òtítọ́ wó wọn túútúú Jẹ́ kí ojú wọn sókùnkùn, kí wọn má sì ṣe ríran Sì jẹ́ kí ẹrù ńlá tẹ̀ wọ́n ba títí láéláé bí wọ́n ti ń rìn lọ Ǹjẹ́ èyí fi hàn wí pé Ọlọ́run àwọn Júù rẹ ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ láéláé Rárá o Ṣe ni Ọlọ́run ń fi ìgbàlà fún àwọn aláìkọlà Nípa síṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí àwọn Júù jowú, kí wọn sì béèrè ìgbàlà Ọlọ́run náà fún ara wọn Bí ó bá ṣe pé gbogbo ayé di ọlọ́rọ̀ nípa ìgbàlà tí Ọlọ́run fifún àwọn Júù nítorí pé wọ́n kọ ìgbàlà náà, ìbùkún tí ó tóbi jùlọ ni yóò tún jẹ́ fún wa nígbà tí àwọn Júù fúnra wọn yóò tún ní ìgbàlà náà pẹ̀lú wa Ṣebí ẹ̀yin náà mọ̀ pé Ọlọ́run ti yà mi sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ajíyìnrere fún àwọn aláìkọlà Mo ń tẹnumọ́ ọn gidigidi mo sì ń rán àwọn Júù létí nípa rẹ̀ nígbákùúgbà tí ààyè bá wà Ìdí tí mo fi ń ṣe èyí ni láti mú kí wọn jowú nǹkan tí ẹ̀yin aláìkọlà ní, bóyá ní ọ̀nà yìí Ọlọ́run lè lò mí láti gba díẹ̀ là nínú wọn Ohun ìyanu ni yóò jẹ́ nígbà tí àwọn Júù yóò di Kírísítẹ́nì Nígbà tí Ọlọ́run yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ṣe ni ó yípadà sí àwọn ìyókù ní ayé láti fún wọn ní ìgbàlà Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú nísinsinyí ìyanu náà ń peléke sí i ni nígbà tí àwọn Júù bá wá sọ́dọ̀ Kírísítì Bí ẹni pé a sọ àwọn òkú di alààyè ni yóò jẹ́ Níwọ̀n ìgbà tí Ábúráhámù àti àwọn wòlíì jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pẹ̀lú Ìdí ni pé, bí gbòǹgbò igi bá jẹ́ mímọ́, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú Ṣùgbọ́n a ti ké díẹ̀ nínú ẹ̀ka Ábúráhámù, tí í ṣe àwọn Júù kúrò Ẹ̀yin aláìkọlà, tí a lè wí pé ó jẹ́ ẹ̀ka igi búburú ni a fi sí ipò àwọn Júù Nítorí náà, nísinsinyí, í se é ṣe fún yín láti gba ìbùkún tí Ọlọ́run ṣe ìpinnu fún Ábúráhámù àti àwọn ọmọ rẹ̀, èyí ni pé, ẹ ń pín nínú oúnjẹ ọlọ́ràá tí ó jẹ́ ti igi àrà ọ̀tọ̀ fún Ọlọ́run Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe gbéraga nítorí pé a fi yín sí ipò àwọn ẹ̀ka tí a ké kúrò Nǹkan tí ó mú kí ẹ ṣe pàtàkì ni pé, ẹ jẹ́ ẹ̀ka igi Ọlọ́run yìí Ẹ rántí pé, ẹ̀ka igi lásán ni yín, ẹ kì í ṣe gbòngbò Ó ṣe é ṣe fún un yín kí ẹ wí pé, Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti ké ẹ̀ka igi wọ̀nyí kúrò, tí ó sì fi wá sí ipò wọn, a sàn jù wọ́n lọ Ẹ kíyèsára! Ẹ sì rántí pé, a ké àwọn ẹ̀ka wọ̀n ọn nì tí í ṣe Júù kúrò nítorí pé wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́ Àti pé, ẹ̀yin sì wà níbẹ̀ nítorí pé ẹ̀yin gbàgbọ́ Ẹ má ṣe gbéraga, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀, kí ẹ sì dúpẹ́, kí ẹ sì, máa sọ́ra gidigidi Nítorí pé bí Ọlọ́run kò bá dá àwọn ẹ̀ka igi tí ó fi síbẹ̀ lákọ́kọ́ sí, ó dájú wí pé, kò ní dá ẹ̀yin náà sí Nítorí náà wo ore àti ìkáànú Ọlọ́run lórí àwọn tí ó subú, ìkàánú ṣùgbọ́n lórí ìwọ, ọrẹ, bi ìwọ bá dúró nínú ọrẹ rẹ̀ kí a má bá ké ìwọ náà kúrò Àti àwọn pẹ̀lú, bí wọn kò bá jókòó sínú àìgbàgbọ́, a ó lọ́ wọn sínú rẹ̀, nítorí Ọlọ́run le tún wọn lọ́ sínú rẹ̀ Nítorí bí a bá ti ke ìwọ kúrò lára igi ólífì ìgbẹ́ nípa ẹ̀dá rẹ̀, tí a sì gbé ìwọ lé orí igi ólífì rere lòdì sí ti ẹ̀dá mélòómélòó ni a ó lọ́ àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ẹ̀ka-ìyẹ́ka sára igi ólífì wọn Ará, èmi kò sá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó wà ní òpè ní ti ohun ìjìnlẹ̀ yìí, kí ẹ̀yin má baá ṣe ọlọgbọ́n ní ojú ara yín, pé ìfọ́jú bá Ísírẹ̀lì ní apákan, títí kíkún àwọn aláìkọlà yóò fi dé Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gba gbogbo Ísírẹ́lì là, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé Ní Síónì ni Olúgbàlà yóò ti jáde wá, yóò sì yìí àìwà-bí-Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ Jákọ́bù Èyí sì ni májẹ̀mú mi fún wọn Nígbà tí èmi yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò Nípa ti ìyìn rere, ọ̀ta ni wọ́n nítorí yín bí ó sì ṣe ti ìyànfẹ́ ni, olùfẹ́ ni wọ́n nítorí ti àwọn baba Nítorí àìlábámọ̀ li ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run Nítorí gẹ̀gẹ̀ bí ẹyin kò ti gba Ọlọ́run gbọ́ rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí tí ẹ̀yin rí ànú gbà nípa àìgbàgbọ́ wọn Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn wọ̀nyí tí ó ṣe àìgbọ́ràn nísinsin yìí, kí àwọn pẹ̀lú bá le rí àánú gbà nípa àánú tí a fi hàn yín Nítorí Ọlọ́run sé gbogbo wọn mọ́ pọ̀ sínú àìgbàgbọ́, kí ó le ṣàánú fún gbogbo wọn A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run! Àwámáridí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí, ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ! Nítorí tali ó mọ inú Olúwa Tàbí tani íṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀ Tàbí tani ó kọ́ fifún un, tí a kò sì san padà fún u Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín Èkọ́ Nípa Ìfẹ́ Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́-ìsìn yín tí ó tọ̀nà Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di titun ní ìrò-inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ̀ntún-wọ̀nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olukúkùlù Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà pípọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ pípọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kírísítì, àti olukúlùkú ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀ Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀-ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí ore-ọ̀fẹ́ tí a fifún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́ Tàbí iṣẹ́-ìránṣẹ́, kí a kọjúsí iṣẹ́-ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́ Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì ẹni tí ń sàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn Ẹ máa takéte sí ohun tí í ṣe búrubú ẹ faramọ́ ohun tí í ṣe rere Níti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín níti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkéjì yín ṣájú Níti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ ẹ máa ní ìgbóná ọkàn ẹ máa sìn Olúwa Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú ẹ máa dúró gangan nínú àdúrà Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́ ẹ fi ara yín fún àlejò íṣe Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè Àwọn tí ń yọ̀, ẹ má bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkùn, ẹ má bá wọn sọkún Ẹ má wà ní inú kan náà sí ara yín Ẹ má ṣe ronú ohun gíga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé onírẹ̀lẹ̀ Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn Bí ó le ṣe, bí ó ti wà ní ipa ti yín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Olùfẹ́, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, Èmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san Ṣùgbọ́n bí ebi bá ń pa ọ̀ta rẹ Fún un ní oúnjẹ bí oùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí Má ṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú Síṣe Ìgbọ́ran Sí Àwọn Aláṣẹ Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run li a ti lànà rẹ̀ wá Nítorí ẹni tí ó bá tàpá sí àṣẹ, ó tàpá sí ìlànà Ọlọ́run àwọn ẹni tí ó ba sì ń tàpá, yóò gba ẹ̀bi fún ara wọn Nítorí pé adájọ́ kò wá láti dẹ́rù ba àwọn ẹni tí ń se rere Ṣùgbọ́n àwọn tó ń ṣe búburú yóò máa bẹ̀rù rẹ̀ nígbà gbogbo Nítorí ìdí èyí, pa òfin mọ́ ìwọ kò sì ní gbé nínú ìbẹ̀rù Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni láti ṣe ọ́ ní rere Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣé nǹkan búburú, máa bẹ̀rù, nítorí kò ru idà náà lásán Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run nííse, ìránṣẹ́ ìbínú sí ara àwọn ẹni tí ń ṣe búburú Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti tẹríba fún àwọn alásẹ, kì í ṣe nítorí ìjìyà tó lé wáyé nìkan, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí-ọkàn pẹ̀lú San owó orí rẹ pẹ̀lú nítorí ìdí méjì pàtàkì tí a ti sọ wọ̀nyí Nítorí pé ó se dandan kí a san owó oṣù fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Èyí yóò mú kí wọn tẹ̀ṣíwájú nínú iṣẹ́ Ọlọ́run náà Wọn yóò sì máa tọ́jú yín Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo owó-orí fún ẹni tí owó-orí tọ́ sí owó-bodè fún ẹni tí owó-bodè tọ́ sí ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù ń ṣe tirẹ̀ ọlá fún ẹni tí ọlá ń ṣe tirẹ̀ Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ní nígbésè, yàtọ̀ fún gbésè ìfẹ́ láti fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já Àwọn òfin, Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panságà, Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè, Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké, bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ sọ̀kan nínú òfin kan yìí Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀ Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀ nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin Àti èyí, bí ẹ ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsìnyí fún yín láti jí lójú orun nítorí nísinsìn yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́ nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀ Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmọ̀tipara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì íṣe ní ìjà àti ìlara Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jésù Kírísítì Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti ma mú ìfẹ́kúfẹ rẹ̀ ṣẹ Aláìlera Àti Alágbára Ẹ gba ẹni tí ó bá ṣe àìlera ní ìgbàgbọ́ mọ́ra, kí ẹ má se tọpinpin ìṣiyèméjì rẹ̀ Ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fi ààyè gbà á láti jẹ ohun gbogbo sùgbọ́n ẹlòmíràn tí ó sì jẹ́ aláìlera ní ìgbàgbọ́ ń jẹ ewébẹ̀ nìkan Kí ẹni tí ń jẹ ohun gbogbo má ṣe kẹ́gàn ẹni tí kò jẹ kí ẹni tí kò sì jẹ ohun gbogbo kí ó má ṣe dá ẹni tí ń jẹ lẹ́bi nítorí Ọlọ́run ti gbà á Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ tí kì í se tìrẹ lẹ́jọ́ Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun ni dúró, tàbí subú Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró Àwọn kan bu ọlá fún ju ọ̀kan lọ, ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú nípa èyí tí ó tọ́ lọ́kàn ara rẹ̀ Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láàyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀ Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa Nítorí náà, yálà ní kíkú tàbí ní yíyè, ti Olúwa ni àwá jẹ́ Nítorí ìdí èyí náà ni Kírísítì fi kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààye Èése nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arakùnrin rẹ lẹ́jọ́ tàbì èése tí ìwọ sì ń fi ojú ẹ̀gàn wo arakùnrin rẹ Nítorí olúkúlùkù wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run A ti kọ ìwé rẹ̀ pé  Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, ni Olúwa wí gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run   Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a yé dá ara wa lẹ́jọ́ Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má se fi òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arakùnrin yín Bí ẹni tí ó wà nínú Jésù Olúwa, mo mọ̀ dájú gbangba pé kò sí oùnjẹ tó jẹ́ àìmọ́ nínú ara rẹ̀ Ṣùgbọ́n bí ẹnìkẹ́ni ba kà á sí àìmọ́, òun ni ó se àìmọ́ fún Bí inú arakùnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí ohun tí ìwọ́ jẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́ Má se fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kírísítì kú fún di ẹni ègbé Má se gba kí a sọ̀rọ̀ ohun tí ó gbà sí rere ní buburu Nítorí ìjọba ọ̀run kì í se jíjẹ àti mímu, bí kò se nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Èmí Mímọ́, nítorí ẹni tí ó bá sin Kírísítì nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó se ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti máa lépa àlàáfíà, àti ohun tí àwa yóò fi gbé ara wa ró Má se dí iṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ nítorí oúnjẹ Gbogbo oúnjẹ ni ó mọ́, sùgbọ́n ohun búburú ni fún ẹni náà tí ó jẹ ohunkóhun tí ó le mú arákùnrin rẹ kọsẹ̀ Ó sàn kí a má jẹ ẹran tàbí mu wáìnì tàbí se ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin rẹ subú Nítorí náà, ohun tí ìwọ bá gbàgbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí, pa á mọ́ ní àárín ìwọ àti Ọlọ́run Alábùkún fún ni ẹni náà tí kò dá ara rẹ̀ lẹ́bi nípa ohun tí ohun gbà Ṣùgbọ́n ẹni náà tí ó se iyèméjì ni a ti dá lẹ́bi tí ó ba jẹ ẹ́, nítorí kò wá nípa ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ sì ni, ohun gbogbo tí kò bá ti ipa ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀sẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù Wàásù Sí Àwọn Aláìkọlà Àwa tí a jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yẹ kí ó máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a má si ṣe ohun tí ó wu ara wa Olúkúlùkù wa gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó wu ọmọnìkejì rẹ̀ sí rere, láti gbé e ró Nítorí Kírísítì pàápàá kò ṣe ohun tí ó wu ara rẹ̀, ṣùgbọ́n, bí a ti kọ ọ́ pé Àwọn ẹni tí ń tàbùkù rẹ ń tàbùkù mi pẹ̀lú Nítorí ohun gbogbo tí a kọ nígbà àtijọ́ ni a kọ láti fi kọ́ wa, kí àwa lè ní ìrètí nípa sùúrù àti ìtùnú èyí tí ó wá láti inú ìwé mímọ́ Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin ní ẹ̀mí ìrẹ́pọ̀ láàrin ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jésù Kírísítì, kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọkàn kan àti ẹnu kan fi ògo fún Ọlọ́run, Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kírísítì ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run Mo sì wí pé, a rán Kírísítì láti ṣe ìránṣẹ́ àwọn tí se Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀, kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrin àwọn aláìkọlà, Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ Ó sì tún wí pé, Ẹ̀yin aláìkọlà, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ Àti pẹ̀lú, Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin aláìkọlà ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo Àìṣáyà sì tún wí pé, Gbòngbò Jésè kan ń bọ̀ wá, òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn aláìkọlà Àwọn aláìkọlà yóò ní ìrètí nínú rẹ̀ Njẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yín ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrétí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, è pé ní ìmọ̀, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín Mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fifún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti jẹ́ ìránsẹ́ Kírísìtì Jésù láàrin àwọn aláìkọlà láti polongo ìyìn rere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúse àlùfáà, kí àwọn aláìkọlà lè jẹ́ ẹbọ-ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí mímọ́ yà sí mímọ́ Nítorí náà, mo ní ìsògo nínú Kírísítì Jésù nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run Èmi kò sa à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò se èyí tí Kírisítì ti ọwọ́ mi se, ní títọ́ àwọn aláìkọlà sọ́nà láti ṣe ìgbọ́ran sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi nípa agbára isẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí a se lọ́wọ́ Ẹ̀mi Mo ti polongo ìyìn rere Kírísítì ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ láti Jérúsálẹ́mù dé ìlú tí a ń pè ní Ílíríkónì Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìyìn rere Kírísítì ní ibi gbogbo tí wọn kò tí i gbọ́ nípa rẹ̀, kí èmi kí ó má se máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé Àwọn tí kò tí ì sọ òrọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i, yóò sì yé àwọn tí kò tí ì gbọ́ ọ rí Ìdí nì yìí tí ààyè fi há pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ fún mi kí n tó wa bẹ̀ yín wò Ṣùgbọ́n báyìí tí kò tún sí ibòmíràn fún mi mọ́ ní agbègbè yìí, tí èmi sì ti ń pòùngbẹ láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn láti tọ̀ yín wá, mo gbèrò láti se bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo bá lọ sí orílẹ̀ èdè Sípáníà Èmi yóò bẹ̀ yín wò ní ọ̀nà ìrìnàjò mi, lẹ́yìn tí a bá sì gbádùn ara wa fún ìgbà díẹ̀, ẹ ó kún mi ọ́wọ́ nínú ìrìnàjò mi láti dé ibẹ̀ Ṣùgbọ́n ní báyìí, mo ń lọ nínú ìrìnàjò sí ìlú Jérúsálẹ́mù láti sé ìránsẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀ Nítorí pé àwọn tí ó wà ní agbégbé Makedóníà àti agbégbé Ákáyà ti kó ẹ̀bùn jọ fún àwọn talákà tí ó wà ní àárín àwọn ènìyàn mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù Pẹ̀lú ayọ̀ ni wọ́n ń se èyí, nítorí wọ́n gbà wí pé, wọ́n jẹ́ ajigbésè fún wọn Nítorí bí ó bá se pé a fi àwọn aláìkọlà se alájọni nínú ohun ẹ̀mí wọn, ajigbèsè sì ni wọn láti fi ohun ti ara ta wọ́n lọ́rẹ Nítorí náà, nígbà tí mo bá ti se èyí tán tí mo bá sì di ẹ̀dìdì èso náà fún wọn tán, èmi yóò gba ti ọ̀dọ̀ yín bí mo bá ń lọ sí orílẹ̀ èdè Sípáníà Mo sì mọ̀ pé nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín, èmi yóò wà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbùkùn Kírísítì Èmí rọ̀ yín, ẹ̀yin ará, nítorí Olúwa wa Jésù Kírísítì, àti nítorí ìfẹ́ Ẹ̀mí, kí ẹ̀yin kí ó kún mi láti bá mi làkàkà nínú àdúrà yín sí Ọlọ́run fùn mi Kí a lè kó mi yọ kúrò lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Jùdíà àti kí isẹ́ ìránsẹ́ tí mo ní sí Jérúsálẹ́mù le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀ Nítorí náà, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run kí èmi le fi ayọ̀ tọ̀ yín wa, kí pọ̀ pẹ̀lú yín ní ìtura Kí Ọlọ́run àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín Àmín Ìkíni Mo fi Fébè arábìnrin wa le yin lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ díaókọ́nì nínú ìjọ tí ó wà ní Kéńkíríà Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ẹ̀nìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú Ẹ kí Pìrìsílà àti Àkúílà, àwọn tí ó ti jẹ́ alábásiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kírísítì Jésù Àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wéwu nítorí mi Kì í se èmi nìkan àti gbogbo àwọn ìjọ àwọn aláìkọlà ní ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn Kí ẹ sì kí ìjọ tí ń pé jọ fún pọ̀ ní ilé wọn Ẹ kí Épénétù ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó di Kírísítẹ́nì ní orílẹ̀ èdè Ésìà Ẹ kí Màríà, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun fún yin Ẹ kí Áńdíróníkúsì àti Júníásì, àwọn ìbátan mi tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi Àwọn wọ̀nyí ní ìtayọ láàrin àwọn àpósítélì, wọ́n sì ti wà nínú Kírísítì sáájú mi Ẹ kí Áńpílíátúsì, ẹni tí ó jẹ́ olùfẹ́ mi nínú Olúwa Ẹ kí Úbánúsì, alábásisẹ́ pọ̀ wa nínú Kírísítì àti olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n Sítákì Ẹ kí Ápẹ́lẹ́sì, ẹni tí a mọ̀ dájú nínú Kírísítì Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Árísítóbúlúsì Ẹ kí Héródíónì, ìbátan mi Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Nákísísù tí wọ́n wá nínú Olúwa Ẹ kí Tírífẹ́nà àti Tírífósà, àwọn obìrin tí wọ́n se iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa Ẹ kí Pásísì ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, obìnrin mìíràn tí ó se iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa Ẹ kí Rúfọ́ọ̀sì, ẹni tí a yàn nínú Olúwa, àti ìyá rẹ̀ àti ẹni tí ó ti jẹ́ ìyá fún èmi náà pẹ̀pú Ẹ kí Ásínkírítúsì, Fílégónì, Hérímésì, Pátíróbà, Hérímásì àti àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú wọn Ẹ kí Fílólóhù, àti Júlíà, Néréù, àti arábìnrin rẹ̀, àti Ólíḿpà, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà pẹ̀lú wọn Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín Gbogbo ìjọ kírísitì kí yín Èmí rọ̀ yín, ara, kí ẹ máa sọ àwọn tí ń fa ìyapa, àti àwọn tí ń mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá sí ọ̀nà yín, èyí tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin kọ́ Ẹ yà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kírísítì Olúwa wa, bí kò se ikùn ara wọn Nípa ọ̀rọ̀ geere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà Nítorí ìgbọ́ràn yín tàn kálẹ̀ dé ibi gbogbo , nítorí náà mo ní ayọ̀ lórí yín ṣùgbọ́n èmi fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n sí ohun tí ó ṣe rere, kí ẹ sì ṣe òpè sí ohun tí í ṣe búburú Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Sátanì mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí Oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín Tìmótíù alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lúkíúsì, àti Jásónì, àti Sósípátérù, àwọn ìbátan mi, kí yín Èmi Térítíù tí ń kọ Èpísítélì yí, kí yín nínú Olúwa Gáíúsì, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó se náà fi ìkíni ránsẹ́ Érásítù, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó isẹ́ ìlú, àti arákùnrin wa Kúárítù fi ìkíni wọn ránsẹ́ Ǹjẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín Àmín Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹṣẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìyìn rere mi àti ìpolongo Jésù Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí ìsípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé, ṣùgbọ́n, nísinsinyí, a ti fihàn, a sì ti sọ ọ́ di mímọ̀ nípa àkọsílẹ̀ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbàgbọ́, kí wọn sì le se ìgbọ́ràn sí i pẹ̀lú kí ògo wà fún Ọlọ́run, Ẹnì kan ṣoṣo tí ọgbọ́n í se tirẹ̀ nípa Jésù Kírísítì! Àmín Ìdájọ́ Òdodo Ọlọ́run Nítorí náà, aláìríwí ni ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́ tí ń dáni lẹ́jọ́ nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣe ìdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi nítorí ìwọ tí ń dájọ́ ń ṣe ohun kan náà nínú èyí tí ìwọ ń dáni lẹ́jọ́ Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́ si gbogbo àwọn tí ó ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí Nítorí bí ìwọ tí ń ṣe ènìyàn lásán bá ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí, tí ìwọ tikararẹ ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ ro èyí pé ìwọ o yọ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run bí Tàbí ìwọ ń gàn ọrọ̀ oore àti ìpamọ́ra àti sùúrù rẹ̀ Ìwọ kò ha mọ̀ pé oore Ọlọ́run ni ó ń fà ọ́ lọ sì ìrònúpìwàdà Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí líle àti àìronúpìwàdà ọkàn rẹ̀, ìwọ ń to ìbínú jọ fún ara rẹ de ọjọ́ ìbínú àti ìfihàn ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run Ọlọ́run yóò san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ Àwọn ẹni tí ń fi sùúrù nínú rere ṣíṣe, wá ògo àti ọlá àti àìdíbàjẹ́ ni yóò fi ìyè àínìpẹ̀kun fún Ṣùgbọ́n fún àwọn onímọ̀-tara-ẹni-nìkan, tí wọn kò sì gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọn ń ẹ̀lé búburú, wọn yóò ní ìrírí ìrúnú àti ìbínú rẹ̀ Ìpọ́njú àti ìrora, yóò wà lórí olúkúlùkù ọkàn ènìyàn tí ń hùwà ibi ti Júù ṣáájú, àti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú Nítorí Olúwa kìí ṣe ojú ìsáájú ènìyàn Gbogbo àwọn tí ó sẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dálẹ́jọ́ Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni aláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dáláre Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà àdánidá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsìnyí Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jésù Kírísítì ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere mi Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálò rẹ̀ sí Ọlọ́run, Tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dárajù lọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin Tí o sì dá ara rẹ lójú pé ìwọ ni amọ̀nà àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ni òkùnkùn, Olùkọ́ àwọn aláìmòye, olùkọ́ àwọn ọmọdé, ẹni tí ó ní ètò ìmọ̀ àti òtítọ́ òfin lọ́wọ́, Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí Ìwọ tí o kóríra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹ́ḿpìlì ní olè bí Ìwọ ti ń ṣògo nínú òfin, ìwọ ha ń bu Ọlọ́run ni ọlá kù nípa rírú òfin Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ, Orúkọ Ọlọ́run sáà di ìsọ̀rọ̀-òdì sí láàrin àwọn aláìkọlà nítorí yín, Nítorí ìkọlà ní èrè nítòótọ́, bí ìwọ bá pa òfin mọ́ ṣùgbọ́n bí ìwọ bá jẹ́ arúfin, ìkọlà rẹ di àìkọlà Nítorí náà bí àwọn aláìkọlà bá pa ìlànà òfin mọ́, a kì yóò ha kà wọ́n sí àwọn tí akọ nílà bí Aláìkọlà nípa àdánidá, bí ó bá pa òfin mọ́, yóò dá ẹ̀bi fún ìwọ tí ó jẹ́ arúfin nípa ti àkọsílẹ̀ òfin àti ìkọlà Kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní òde ni Júù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní ara ni ìkọlà Ṣùgbọ́n Júù ti inú ni Júù, àti ìkọlà sì ni ti ọkàn nínú ẹ̀mí tí kì í ṣe ti àkọsílẹ̀, ìyìn ẹni tí kò sí lọ́dọ̀ ènìyàn, bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run Ìsòtítọ́ Ọlọ́run Ǹjẹ́ àǹfààní wo ní Júù ní Tàbí kín ni èrè ilà kíkọ Púpọ̀ lọ́nà gbogbo pàtàkì jùlọ ni pé àwọn ni a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé lọ́wọ́ Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́ Àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọ́run di asán bí Kí a má rí i kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́ Ṣùgbọ́n bí àìṣòdodo wa bá fi òdodo Ọlọ́run hàn, kín ni àwa ó wí Ọlọ́run ha jẹ́ àìsòdodo bí Nígbà tí ó bá ń fi ìbínú rẹ̀ hàn Kí a má rí i bí bẹ́ẹ̀ bá ni, Ọlọ́run yóò ha ṣe lè dájọ́ aráyé Nítorí bí òtítọ́ Ọlọ́run bá di púpọ̀ sí ìyìn rẹ̀ nítorí èké mi, èéṣe tí a fi ń dá mi lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́sẹ̀ Èéṣe tí a kò fi ṣe búburú kí rere lè jáde wá Bí àwọn kan tí ń fi ẹnu àtẹ́ sọ wí pé a ń sọ bẹ́ẹ̀ ti àwọn kan sì ń tẹnumọ́ ọn pé a sọ àwọn ẹni tí ìdálẹ́bí wọn tọ́ Ǹjẹ́ kí ha ni Àwa ha sàn wọn bí Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá nítorí a fi hàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Gíríkì, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan Kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run Gbogbo wọn ni ó ti yapa, wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè kò sí ẹni tí ń ṣe rere, kò tilẹ̀ sí ẹnìkan Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní Ọ̀fun wọn ahọ́n wọn di aláìlérè kò sí ẹni ìtànjẹ Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ Ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀ Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀ nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá Ṣùgbọ́n nisinsinyìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nítorí tí kò sí ìyàtọ̀ Gbogbo ènìyàn ni ó sá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run Àwọn ẹni tí a ń dáláre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kírísítì Jésù Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsìnyìí kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáre ẹni tí ó gba Jésù gbọ́ Ọ̀nà ìṣògo dà A ti mú un kúrò Nípa òfin wo Nípa iṣẹ́ Bẹ́ẹ̀ kọ́ Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́ Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, tí yóò dá àwọn akọlà láre nípa Ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nítorí ìgbàgbọ́ wọn Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí Kí a má rí i ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀ Ábúráhámù Gba Ìdálòre Nípa Ìgbàgbọ́ Ǹjẹ́ kín ni àwa ó ha wí nípa Ábúráhámù, baba wa sàwárí nípa èyí Májẹ̀mu láéláé jẹ́rìí si i wí pé, a gba Ábúráhámù là nípa ìgbàgbọ́ Nítorí bí a bá dá Ábúráhámù láre nípa iṣẹ́, ó ní ohun ìṣògo ṣùgbọ́n kì í ṣe níwájú Ọlọ́run Ìwé mímọ́ ha ti wí Ábúráhámù gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ṣiṣẹ́, a kò ka èrè náà sí oore ọ̀fẹ́ bí kò ṣe sí ẹ̀tọ́ rẹ̀ Ṣùgbọ́n fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́, tí ó sì ń gba ẹni tí ó ń dá ènìyàn búburú láre gbọ́, a ka ìgbàgbọ́ rẹ̀ sí òdodo Gẹ́gẹ́ bí Dáfídì pẹ̀lú ti pe olúwa rẹ̀ náà ní ẹni ìbùkún, ẹni tí Ọlọ́run ka òdodo fún láìsí ti iṣẹ́ Wí pé, Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí a dárí ìrékọjá wọn jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀ Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn Ìbùkún yìí ha jẹ́ ti àwọn akọlà nìkan, tàbí ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú Nítorí tí a wí pé, a ka ìgbàgbọ́ fún Ábúráhámù sí òdodo Báwo ni a ṣe kà á sí i Nígbà tí ó wà ní ìkọlà tàbí ní àìkọlà Kì í ṣe ni ìkọlà, ṣùgbọ́n ní àìkọlà ni Ó sì gbé àmì ìkọlà, èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún ṣá, ṣùgbọ́n ti wọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Ábúráhámù ní, kí a tó kọ ọ́ nílà Ìlérí fún Ábúráhámù àti fún irú ọmọ rẹ̀, pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́ Nítorí bí àwọn tí ń ṣe ti òfin bá ṣe ajogún, ìgbàgbọ́ di asán, ìlérí sì di aláìlágbára Nítorí òfin ń ṣiṣẹ́ ìbínú Ṣùgbọ́n ní ibi tí òfin kò bá sí, ìrúfin kò sí níbẹ̀ Nítorí náà ni ó ṣe gbé e karí ìgbàgbọ́, kí ìlérí náà bá a lè sinmi lé oore-òfẹ́, kí a sì lè mú un dá gbogbo irú ọmọ lójú, kì í ṣe fún àwọn tí ń pa òfin mọ́ nìkan, ṣùgbọ́n bí kò ṣe pẹ̀lú fún àwọn ti ó pín nínú ìgbàgbọ́ Ábúráhámù, ẹni tí í se baba gbogbo wa pátapáta, Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, Mo ti fi ọ́ se baba orílẹ̀ èdè púpọ̀ Níwájú Ọlọ́run ẹni tí òun gbàgbọ́, ẹni tí ó sọ òkú di ààyè, tí ó sì pè àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Ábúráhámù gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀ èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyi tí a wí fún un pé, Báyìí ni irú ọmọ rẹ̀ yóò rí Ẹni tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́, nígbà tí ó ro ti ara òun tìkarárẹ̀ tí ó ti kú tan, nítorí tí ó tó bí ẹni ìwọ̀n ọgọ́rún-ún ọdún, àti nígbà tí ó ro ti yíyàgàn inú Sárà Kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì nípa ìlérí Ọlọ́run ṣùgbọ́n ó lágbára sí i nínú ìgbàgbọ́ bí ó ti fi ògo fún Ọlọ́run Pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé, Ọlọ́run lè ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ̀ Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, A kà á sí òdodo fún un, ni a kọ kì í ṣe kìkì nítorí tirẹ̀ nìkan Ṣùgbọ́n nítorí tiwa pẹ̀lú A ó sì kà á sí fún wa, bí àwa bá gba ẹni tí ó gbé Jésù Olúwa wa dìde kúrò nínú òkú gbọ́ Ẹni tí a pa fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde nítorí ìdáláre wa Àlááfíà Àti Ayọ̀ Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípaṣẹ̀ Olúwa wa Jésù Kírísítì Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń sisẹ́ sùúrù Àti pé sùúrù ń siṣẹ́ ìrírí àti pé ìrírí ń siṣẹ́ ìrètí Ìrètí kì í sì í dójútini nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kírísítì kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀, Kírísítì kú fún wa Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinn yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípaṣẹ̀ rẹ̀ Ǹjẹ́ bí, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀ Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jésù Kírísítì, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsìn yìí Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́sẹ̀ Nítorí kí òfin tó dé, ẹ̀ṣẹ̀ ti wà láyé ṣùgbọ́n a kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ni lọ́rùn nígbà tí òfin kò sí Ṣùgbọ́n ikú jọba láti ìgbà Ádámù wá títí fi di ìgbà ti Mósè, àti lórí àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò dàbí irú ìrékọjá Ádámù, ẹni tí í ṣe àpẹẹrẹ ẹni tí ń bọ̀ Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ kò dàbí ẹ̀ṣẹ̀ Nítorí bí nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ẹni púpọ̀ kú, mélòó mélòó ni oore-ọ̀fẹ́ ọkùnrin kan, Jésù Kírísítì, di púpọ̀ fún ẹni púpọ̀ Kì í ṣe bí nípa ẹnìkan tí ó sẹ̀ ni ẹ̀bùn náà Nítorí ìdájọ́ ti ipasẹ̀ ẹnìkan wá fún ìdálẹ́bi, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ ti inú ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ wá fún ìdáláre, Ǹjẹ́ bí nípa ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin kan, ikú jọba nípasẹ̀ ẹnìkan náà mélòó mélòó ni àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bùn òdodo yóò jọba nínú ìyè nípasẹ̀ ẹnìkan, Jésù Kírísítì Ǹjẹ́ bí nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ìdájọ́ dé bá gbogbo ènìyàn sí ìdálẹ́bi gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nípa ìwà òdodo ẹnìkan, ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ dé sórí gbogbo ènìyàn fún ìdáláre sí ìyè Nítorí gẹ́gẹ́ bí nípa àìgbọ́ràn ọkùnrin kan, ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́sẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọ́ràn ẹnìkan, a ó sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo Ṣùgbọ́n òfin bọ́ sí inú rẹ̀, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè di púpọ̀, ṣùgbọ́n ni ibi ti ẹ̀ṣẹ̀ di púpọ̀, oore-ọ̀fẹ́ di púpọ̀ rékọjá Pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti jọba nípa ikú bẹ́ẹ̀ ni kí oore-ọ̀fẹ́ sì lè jọba nípa òdodo títí ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa Ikú Sí Ẹ̀sẹ̀, Ìyè Nínú Kírísítì Ǹjẹ́ àwa ó ha ti wí Ṣé kí àwa ó jòkòó nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí oore-ọ̀fẹ́ ba à lè máa pọ̀ sí i Kò lè rí bẹ́ẹ̀ Ṣé a tún le máa dẹ́sẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fún wa ní ìṣẹ́gun lórí rẹ̀ Nítorí a ti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí a di Kírísítẹ́nì tí a sì ṣe ìrìbọmi fún wa láti di apá kan Jésù Kírísítì nípasẹ̀ ikú rẹ̀, a borí agbára ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Ẹ ti gbé ògbólógbòó ara yín tí ń fẹ́ máa dẹ́sẹ̀ sin pẹ̀lú Kírísítì nígbà tí òun kú, àti nígbà tí Ọlọ́run Baba pẹ̀lú agbára ògo mú un padà sí ìyè, a sì fún yín ní ìyè tun tun rẹ̀ láti gbádùn rẹ̀, èyí ṣẹlẹ̀ nípa ìrìbọmi yín Nítorí pé ẹ̀yin ti di apá kan ara rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde Gbogbo èrò burúkú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́sẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀ Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́ Níwọ̀n ìgbà tí ògbólógbòó ara yín tó ń fẹ́ máa dẹ́sẹ̀ ti kú pẹ̀lú Kírísítì, àwa mọ̀ pé, ẹ̀yin yóò pín nínú ìyè titun rẹ̀ Kírísítì ti jí dìde kúrò nínú òkú Òun kò sì ní kú mọ́ Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́ Kírísítì kú lẹ́ẹ̀kan soso, láti sẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láàyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run Nítorí náà, ẹ máa wo ògbólógbòó ara ẹ̀ṣẹ̀ yín gẹ́gẹ́ bí òkú tí kò ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ Dípò èyí, máa gbé ìgbé ayé yín fún Ọlọ́run nìkan ṣoṣo Ẹ dúró gbọn-in gbọn-in fún un, nípasẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa Nítorí náà kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀sẹ̀ jọba lórí ara kíkú yín kí ó lè ba à máa ṣe ìfẹ́kùfẹ̀ẹ̀ rẹ̀ Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ara yín kan di ohun èlò ìkà, nípa ẹ̀ṣẹ̀ dídá Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ǹda wọn fún Ọlọ́run pátápátá Wọ́n ti di ààyè, ẹ jẹ́ kí wọn di ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí ó lè lò wọ́n fún àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó dára Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́ Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé, nísinsinyìí, a lè tẹ̀ṣíwájú láti máa dẹ́ṣẹ̀ láì bìkítà Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́ Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìgbọ́ràn Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá yọ̀ǹda ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀ Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti se ìgbọ́ràn, pẹ̀lú ọkàn yín, sí ẹ̀kọ́ èyí tí Ọlọ́run fi lé yín lọ́wọ́ Nísinsìnyìí, ẹ ti dòminira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tíí ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo Èmi ń sọ̀rọ̀ lọ́nà báyìí, ní lílo àpèjúwe àwọn ẹrú àti àwọn ọ̀gá nítorí kí ó ba le yé yín Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú sí oríṣiríṣi ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ ní láti di ẹrú gbogbo èyí tíi ṣe rere tí ó sì jẹ́ Mímọ́ Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin kò ṣe wàhálà púpọ̀ pẹ̀lú òdodo Àti pé, kí ni ìyọrísí rẹ̀ Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára Níwọ̀n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsìnyìí láti ronu nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń sọ nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ìránṣẹ́ Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àìnípẹ̀kun nípaṣẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa Àpèjúwe Kan Láti Inú Ìgbèyàwó Ẹ̀yin kò ha mọ̀, ara nítorí èmí bá àwọn tí ó mọ òfin sọ̀rọ̀ pé, òfin ní ipá lórí ènìyàn níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láàyè nìkan Fún àpẹẹrẹ, nípa òfin ní a de obìnrin mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ náà wà láàyè, ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, a tú u sílẹ̀ kúrò nínú òfin ìgbéyàwó náà Nígbà náà, bí ó bá fẹ́ ọkùnrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyé, panṣagà ní a ó pè é Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin náà, kí yóòsì jẹ́ panṣagà, kódà bí ó bá ní ọkọ mìíràn Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ti di òkú sí òfin nípa ara Kírísítì, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹlòmìíràn, àní ẹni náà tí a jí dìde kúrò nínú òkú, kí àwa kí ó lè so èso fún Ọlọ́run Nítorí ìgbà tí ìfẹ́kúfẹ́ ara ń darí wa, ar ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nípa òfin, ó ń ṣisẹ́ nínú àwọn ara wa láti so èso fún ikú Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, nípa kíkú láti ipasẹ̀ ohun tó so wápọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í se ní ìlànà ti àtijọ́ tí òfin gùnlé Ǹjẹ́ àwa o ha ti wí, nígbà náà Òfin ha ń ṣe ẹ̀ṣẹ̀ bí Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n èmi kì bá tí mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, bí kò ṣe nípa òfin Èmi kì bá tí mọ ojúkòkòrò, bí kò ṣe bí òfin ti wí pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ sì ti ipa òfin rí àyè ṣíṣẹ onírúurú ìfẹ́kúfẹ́ nínú mi Nítorí láìsí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ikú Èmi sì ti wà láàyè láìsí òfin nígbà kan rí ṣùgbọ́n nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ sọjí èmi sì kú Mo ṣàkíyèsí pé òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá ni ó padà mú ikú wá Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti ipa òfin rí àyè láti tàn mí jẹ, ó sì ti ipa òfin se ikú pa mi Bẹ́ẹ̀ ni mímọ́ ni òfin, mímọ́ sì ni àṣẹ, àti òdodo, àti dídára Ǹjẹ́ ohun tí ó dára ha di ikú fún mi bí Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n kí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè farahàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó ń ti ipa ohun tí ó dára ṣiṣẹ́ ikú nínú mi, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè ti ipa òfin di búburú rékọjá Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń se Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ se gan an n kò se é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kóríra ni mo ń se Ṣùgbọ́n bí mo bá se ohun tí èmi kò fẹ́, mo gbà pé òfin dára Ṣùgbọ́n bí ọ̀rọ̀ se rí yìí kì í se èmi ni ó se é bí kò se ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ mi Èmi fẹ́ se èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe Níorí ohun tí èmi se kì í se ohun rere tí èmi fẹ́ láti se rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, éyí nì ni èmi ń se Nísinsin yìí, bí mo bá ń se nǹkan tí n kò fẹ́ láti se, kì í se ẹ̀mi fúnra mi ni ó se é, bí kò se ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú ni ó se é Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi nígbà tí èmi bá fẹ́ se rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run mo rí òfin mìíràn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi, èyí tí ń gbógun ti òfin tó tinú ọkàn mi wá, èyí tí ó sọ mi di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi Èmi ẹni òsì! Ta ni yóò ha gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ara ikú yìí Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa! Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi fúnraà mi jẹ́ ẹrú sí òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mo jẹ́ ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ Ìyè Nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí Nítorí náà, kò sí ìdálẹ́bi nísinsinyìí fún àwọn tí ó wà nínú Kírísitì Nítorí nípaṣẹ̀òfin ti ẹ̀mí ìyè nínú Kírísítì Jésù ti sọ mí di òmìnira kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú Nítorí ohun tí òfin kò lè ṣe, bí ó ti jẹ aláìlera nítorí ara, Ọlọ́run rán ọmọ òun tìkara rẹ̀ ní àwòrán ara ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ àti bi ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ara, Kí a lè mú òdodo òfin ṣẹ, nínú wa, nítorí tí àwa ve gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí Àwọn tí ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, wọn a máa ronú ohun ti ara ṣùgbọ́n àwọn ti ń e gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí, wọn a máa ronú ohun ti Ẹ̀mí Ṣíṣe ìgbọ́ran sí ẹ̀mí Mímọ́ ń yọrí sí ìyè àti àlàáfíà Ṣùgbọ́n títẹ̀lé ara ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ náà ń yọrí sí ikú Nítorí pé ara ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú wa ń tako Ọlọ́run Ìdí nì yìí tí àwọn tí ó wà lábẹ́ àkóso ara ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ìfẹ́ ibi wọn, kò le è tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ rárá Ara titun yín ni yóò máa se àkóso yín bí ẹ bá ń rìn nípa ẹ̀mí Ọlọ́run tí ń gbé inú yín Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kírísítì ń gbé inú yín ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ẹran ara yín yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú yín yóò fún yín ní ìyè, nítorí ó ti fún un yín ní òdodo Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jésù kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, òun yóò mú kí ara yín tí ó kú tún wà láàyè nípa sẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ kan náà tí ń gbé inú yín Nítorí náà ará, kò jẹ́ ọ̀rọ̀ iyàn fún un yín láti se nǹkan tí ara ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ ń rọ̀ yín láti se Nítorí pé bí ẹ̀yin bá ń tẹ̀lé, ẹ̀ṣẹ̀ ti ara ẹ̀yin yóò sọnù, ẹ ó sì sègbé, ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípaṣẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́, ẹ̀yin sẹ́gun ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ibi rẹ̀ nínú yín, ẹ̀yin yóò yè Nítorí pé, iye àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run Àti pé, àwa kò ní láti dàbí ẹrú tó ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ̀gá rẹ̀ Ṣùgbọ́n a ní láti hùwà bí ọmọ Ọlọ́run Ẹni tí a sọdọmọ sí ìdílé, Ọlọ́run tó sì ń pe Ọlọ́run ní Baba, Baba Nítorí ẹ̀mí mímọ́ ń sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn wa, ó sì ń sọ fún wa pé, ní tòótọ́, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run Níwọ̀n ìgbà tí a jẹ́ ọmọ rẹ̀, àwa yóò pín nínú dúkìá rẹ̀ Nítorí nǹkan gbogbo tí Ọlọ́run fún Jésù ọmọ rẹ̀ jẹ́ tiwa pẹ̀lú, ṣùgbọ́n bí á bá ní láti pín ògo rẹ̀, a ní láti setan láti pín nínú ìjìyà rẹ̀ Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò já mọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run Nítórí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í se bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkáararẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdibàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí Kì í se àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkara wa pẹ̀lú, tí ó nbí àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkara wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìṣọdọmọ àní ìdáńdè ara wa Nítorí ìrètí tí a fi gbà wá là ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í se ìrètí nítorí ta ni ń retí ohun tí ó bá rí Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́ nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkáara rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa Ẹni tí ó sì ń wá ọkàn wò, ó mọ ohun ti inú ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń siṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀ Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, u kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn arákùnrin púpọ̀ Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di aláìjẹ̀bi lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kírísítì kún inú ọkàn wa Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti yọ̀ǹda ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le sòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀ Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dárí jì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀ Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi Ǹjẹ́ Kírísítì Yóò dá wa lẹ́bi Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ó kú fún wa tó sì tún jí ǹ de, nisínsin yìí, Òun jókòó ní ibi tí ó ga jùlọ tí ó lọ́lá, tí ó fara ti Ọlọ́run Òun sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa lọ́run níbẹ̀ Ta ni ó tilẹ̀ le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kírísítì Nígbà tí wàhálà tàbí ìdàmú bá dé, nígbà tí wọ́n bá já wa lulẹ̀ tàbí pa wá Ṣé nítórí pé Ọlọ́run kò fẹ́ràn wa mọ́ ni àwọn nǹkan wọ̀nyí yóò fi sẹlẹ̀ sí wa Àti pé, Bí ebi bá ń pa wá, tàbí kò sí kọ́bọ̀ lọ́wọ́, tàbí a wà nínú ìsòro, tàbí ikú dẹ́rù bà wá, ǹjẹ́ Ọlọ́run ti fi wá sílẹ̀ bí Bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí ìwé mímọ́ sọ fún wa pé Nítorí yín àwa ní láti múra tan fún ikú nígbàkúgbà Àwa dàbí àgùntàn tí ń dúró de pípa Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìṣẹ́gun ni ti wa nípaṣẹ̀ Kírísítì, ẹni tí ó fẹ́ wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó sì fi fún wa Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kò sí ohunkóhun tó lè yà wá nínú ìfẹ́ rẹ̀ Kì í se ikú tàbí ìyè Àwọn ańgẹ́lì àti gbogbo agbára ọ̀run àpáàdì fún raarẹ̀ kò le ya ìfẹ́ Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ wa Ìbẹ̀rù fún wa lónìí, wàhálà nípa ti ọjọ́ ọ̀la Tí ìsòro bá tilẹ̀ ga ju àwọ̀ sánmọ̀ lọ tàbí ní ìsàlẹ̀ omi, ohunkóhun kì yóò lágbára láti yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tí Jésù Kírísítì Olúwa fi hàn nígbà tí ó kú fún wa Ọ̀rọ̀ Lórí Ìpinnu Àti Ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ìbátan mi nípa ti ara, ó wù mí púpọ̀ láti rí i pé ẹ gba Kírísítì gbọ́ Ọkàn mi gbọgbẹ́, mo sì ń joró lọ́sán àti lóru nítorí yín Mo fẹ́ lọ sọ pé ó sàn fún mi kí a yọ orúkọ mi kúrò nínú ìwé Ìyè, kí ẹ̀yin lè rí ìgbàlà Kírísítì pàápàá àti ẹ̀mí mímọ́ pẹ̀lú mọ̀ pé òtítọ́ ọkàn mi ni èmi ń sọ yìí Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run ti fi fún yín Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ẹ kì yóò tẹ́tí sí i Ó yàn yín bí ẹni ọ̀tọ̀ fún ara rẹ̀ Ó sìn yín pẹ̀lú ìtànsán ògo rẹ̀, ó mú kí ó dá a yín lójú pé òun yóò bù kún yín, ó fi òfin fún yín kí ẹ le mọ ìfẹ́ rẹ̀ lójojúmọ́, ó yọ̀ǹda fún yín láti sin òun pẹ̀lú ìpinnu ńlá Baba yín ni àwọn onígbàgbọ́ jàǹkànjàǹkàn àtijọ́ jẹ́ Ọ̀kan nínú yín ni Kírísítì fúnrara rẹ̀ jẹ́ Júù ni òun nínú ara, òun sì ni olùdarí ohun gbogbo Ìyìn ló yẹ kí ẹ máa fifún Ọlọ́run láéláé Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán Kì í sá íṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Ísírẹ́lì wá, àwọn ni Ísírẹ́lì Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú ọmọ Ábúrámù, gbogbo wọn nii ọmọ Ṣùgbọ́n, nínú Ísákì li a ó ti pe irú ọmọ rẹ̀ Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú ọmọ Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí Níwọ̀n àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sárà yóò sì ní ọmọ ọkùnrin Kì sì íṣe kìkì èyí Ṣùgbọ́n nígbà tí Rèbékà pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Ísákì baba wa Nítorí nígbà tí kò tí ì bá àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú, A ti sọ fún un pé, Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé Jákọ́bù ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Ísáù ni mo kóríra Njẹ́ àwa yóò ha ti wí Àìsòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí Kí a má ri! Nítorí ó wí fún Mósè pé, Èmi ó sàánú fún ẹni tí èmi yóò sàánú fún, èmi yóò sì se ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò se ìyọ́nú fún Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í se ti ẹni tí ń sáré, bí kò se ti Ọlọ́run tí ń sàánú Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Fáráò pé, Nítorí èyí ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, kí a sì le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé Nítorí náà ni ó ṣe sàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú lí ọkàn le Ìwọ ó sì wí fún mi pé, kínni ó ha tún bá ni wí fún Nítorí tani ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà Bẹ́ẹ̀ kọ́, Ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn Ohun tí a mọ, a máa wí fún ẹni tí ó mọ ọn pé, Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyì Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí àmọ̀, níní ìṣu kan náà láti ṣe apákan ní ohun èlò sí ọlá, àti apákan ní ohun èlò sí àìlọ́lá Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ń kọ́ Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mímọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mímọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣájú fún ògo, Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn aláìkọlà pẹ̀lú Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hóséà pé, Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi, àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́ Yóò sì ṣe, Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé, ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi, níbẹ̀ ni a ó gbé ti sọ fún wọn pé, ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi, níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ọmọ Ọlọ́run alààyè   Ìsáíà sì kí gbe nnítorí Ísírẹ́lì pé Bí iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá rí bí iyanrìn etí òkun, apákan ni ó gbàlà Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo Àti bí Ìsáià ti wí tẹ́lẹ̀ Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa, àwa ìbá ti dàbí Sódómù, a bá sì ti sọ wá dàbí Gòmórà Ǹjẹ́ kílí àwa ó ha wí Pé àwọn aláìkọlà, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá ni Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo, Nítorí kíni Nítorí wọn kò wá a nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni pé nípa iṣẹ́ òfin Nítorí wọn kọsẹ̀ lára òkúta ni Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ àti àpáta tí ó mú wọn subú kalẹ̀ ní Síónì, ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í Náómì àti Rúùtù Ní ìgbà tí àwọn onídaájọ́ ń ṣe àkóso ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ìyàn kan mú ní ilẹ̀ náà, ọkùnrin kan láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà, òun àti aya rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjì lọ láti máa gbé ní ilẹ̀ Móábù fún ìgbà díẹ̀ Orúkọ ọkùnrin náà ń jẹ́ Elimélékì, orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Náómì, orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì ni Málónì àti Kílíónì àwọn ará Éfúrétà, ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà Wọ́n sì lọ sí ilẹ̀ Móábù, wọ́n ń gbé níbẹ̀ Ní àsìkò tí wọ́n ń gbé ibẹ̀, Elimélékì, ọkọ Náómì kú, ó sì ku òun pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì Wọ́n sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ará Móábù méjì, orúkọ, ọ̀kan ń jẹ́ Órípà, èkejì sì ń jẹ́ Rúùtù Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti gbé níbẹ̀ fún bí ọdún mẹ́wàá, Málónì àti Kílíónì náà sì kú, Náómì sì wà láìsí ọkọ tàbí ọmọ kankan fún-un mọ́ Nígbà tí Náómì gbọ́ ní Móábù tí ó wà wí pé Olúwa ti bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò nípa fí fún wọn ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ Ó sì dìde pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì láti padà sí ìlú rẹ̀ Òun pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì ni wọ́n jọ fi ibi tí ó ń gbé sílẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò wọn padà sí ilẹ̀ Júdà Ṣùgbọ́n ní ojú ọ̀nà, Náómì wí fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé, Kí ẹnikọ̀ọ̀kan yín padà sí ilé ìyá rẹ̀ Kí Olúwa ṣe àánú fún yín bí ẹ ti ṣe sí èmi àti àwọn ọkọ yín tí ó kú Kí Olúwa kí ó fi yín lọ́kàn balẹ̀ ní ilé ọkọ mìíràn Náómì sì fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu wí pé Ó dìgbà, Wọ́n sì sunkún kíkan kíkan Wọ́n sì wí fún-un pé, Rárá, a ó bà ọ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ Ṣùgbọ́n Náómì dáhùn wí pé, Ẹ padà sílé ẹ̀yin ọmọ mi Nítorí kí ni ẹ fi fẹ́ wá pẹ̀lú mi Ṣé mo tún le bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn ni, tí ó le se ọkọ yin Ẹ padà sílé, ẹ̀yin ọmọ mi, mo ti dàgbà jù láti ní ọkọ mìíràn Bí mo ti lẹ̀ ní èrò wí pé ìrètí sì wà fún mi, tí mo sì fẹ́ ọkọ mìíràn lónìí tí mo sì bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn, ṣé ẹ̀yin le è dúró dìgbà tí wọ́n bá dàgbà láì fẹ́ ọkọ mìíràn nítorí wọn ni Rárá, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi Ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún mi ju bí ó ti jẹ́ fún ẹ̀yin lọ nítorí pé ọwọ́ Olúwa ti fìyà jẹ mi lọ́nà tó pamí lára gidi Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n tún sunkún kíkorò Nígbà náà ní Órípà fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ ní ẹnu wí pé ó dìgbà, ṣùgbọ́n Rúùtù dì mọ́ ọn síbẹ̀ Náómì wí pé, Wòó, arábìnrin rẹ ti padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti òrìṣà rẹ̀, ìwọ náà padà pẹ̀lú rẹ̀ Ṣùgbọ́n Rúùtù dáhùn wí pé, Má ṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀ tàbí láti padà lẹ́yìn rẹ Ibi tí o bá lọ ní èmi yóò lọ, ibi ti ó bá dúró ni èmi yóò dúró, àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run, mi, Nibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, níbẹ̀ ni wọn yóò sì sin mí sí Kí Olúwa jẹ mí ní ìyà tí ó lágbára, bí ohunkóhun bí kò ṣe ikú bá yà wá Nígbà tí Náómì rí i wí pé Rúùtù ti pinnu láti tẹ̀lé òun kò rọ̀ láti padà mọ́ Àwọn méjèèjì sì ń lọ títí wọ́n fi dé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ariwo ìpadàbọ̀ wọn gba ìlú kan, àwọn obìnrin ibẹ̀ sì kígbe ní ohùn rara wí pé, Náómì ni èyí bí Náómì sì dáhùn wí pé, Ẹ má ṣe pè mí ní Náómì Ẹ pè mí ní Márà , nítorí wí pé Olódùmarè ti mú kí ayé mi di kíkorò Mo jáde ní kíkún, ṣùgbọ́n Olúwa mú mi padà ní òfo Nítorí náà kíń ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Náómì, nígbà tí Olódùmarè ti kọ̀ mí sílẹ̀, tí ó sì mú ìdààmú bá mi Báyìí ni Náómì ṣe padà láti Móábù pẹ̀lú Rúùtù, ará Móábù ìyàwó ọmọ rẹ̀ Wọ́n gúnlẹ̀ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì Rúùtù Pàdé Bóásì Náómì ní ìbátan kan láti ìdílé Elimélékì ọkọ rẹ̀, aláàánú ọlọ́rọ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bóásì Rúùtù, ará Móábù sì wí fún Náómì pé, Jẹ́ kí èmi kí ó lọ sí inú oko láti ṣa ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí èmi yóò bá ojú rere rẹ̀ pàdé Náómì sì sọ fún-un pé, Má a lọ, ọmọbìnrin mi Rúùtù sì jáde lọ láti ṣa ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ lẹ́yìn wọn Ó wá jẹ́ wí pé inú oko Bóásì tí ó ti ìdílé Elimélékì wá ni ó lọ láé mọ̀ ọ́ mọ̀ Nígbà náà ni Bóásì dé láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó sì kí àwọn olùkórè wí pé, Kí Olúwa wà pẹ̀lú yín Wọ́n sì dá a lóhùn padà pé, Kí Olúwa bùkún fún ọ Bóásì sì béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùkórè wí pé, Ti ta ni ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn Ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olórí àwọn olùkórè náà sì fèsì pé, Ọ̀dọ́mọbìnrin ará Móábù tí ó tẹ̀lé Náómì wá láti ilẹ̀ Móábù ni Ó sọ wí pé, Kí ń jọ̀wọ́ jẹ́ kí òun máa ṣa ọkà lẹ́yìn àwọn olùkórè Ó sì ti ń ṣe iṣẹ́ kárakára láti òwúrọ̀ títí di ìsinsìn yìí nínú oko àyàfi ìgbà tí ó lọ láti sinmi fún ìgbà díẹ̀ lábẹ́ ibojì Nígbà náà ni Bóásì sọ fún Rúùtù pé, Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣa ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin mi Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́ Nígbàkugbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú Rúùtù wólẹ̀, ó sì wí fún Bóásì pé, Èéṣe tí èmi fi bá ojúrere rẹ pàdé tó báyìí, tí o sì kíyèsí mi, èmi àjèjì àti àlejò Bóásì sì fèsì wí pé, Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàárin àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ rí tẹ́lẹ̀ Kí Olúwa kí ó san ẹ̀san ohun tí o ṣe fún ọ Kí o sì gba èrè kíkún láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì abẹ́ ìyẹ́ ẹni tí ìwọ sá wá fún ààbò Rúùtù sì fèsì wí pé, Kí èmi kí ó máa rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ rẹ ṣíwájú sí i olúwa mi Ìwọ ti tù mí nínú nípa sísọ ọ̀rọ̀ rere sí ìránṣẹ́-bìnrin rẹ, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé èmi kò tó ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ Nígbà tí àkókò oúnjẹ sì tó, Bóásì sọ fún Rúùtù pé, Wá gba ìwọ̀n àkàrà yí kí o sì fi run wáìnì kíkan Ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè, Bóásì sì fún-un ní ọkà yíyan Ó sì jẹ́, ó yó, ó sì tún ṣẹ́kù Nígbà tí ó sì dìde láti máa ṣa ọkà, Bóásì pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ wí pé, Bí ó tilẹ̀ ń ṣà láàárin oko ọkà pàápàá, ẹ má ṣe dí i lọ́wọ́ Bí kò ṣe pé kí ẹ mú lára àwọn ìtí sílẹ̀ fún láti ṣa, kí ẹ má sì ṣe ba a wí Rúùtù sì ń ṣa ọkà títí ó fi di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí ó sì pa ọkà tí ó rí ṣà, tí ó sì fẹ́ ẹ tán, èyí tí ó rí sì tó ìwọ̀n garawa kan Ó sì gbé e lọ sí ìgboro, ìyá ọkọ rẹ sì rí ọkà tí ó rí sà bi o tí pọ̀ tó, Rúùtù sì mú oúnjẹ tí ó jẹ kù lẹ́yìn tí ó ti yó tan fún ìyá ọkọ rẹ̀ Ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í léèrè wí pé, Níbo ni ìwọ ti ṣa ọkà lónìí Àti wí pé oko ta ni ìwọ gbé ṣiṣẹ́ Alábùkún fún ni ọkùnrin náà tí ó bojú wò ọ Rúùtù sì sọ ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀ pé, Ní oko ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bóásì ni òun ti ṣiṣẹ́ lónìí Náómì sì wí fún-un pé, Kí Olúwa , kí ó bùkún fún ọkùnrin náà Ọlọ́run kò dáwọ́ oore àti àánú ṣíṣe sí àwọn alààyè àti òkú dúró Náómì sì sọ ṣíwájú sí i wí pé, Ìbátan tí ó súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ni ọkùnrin náà ń ṣe, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹ̀tó láti ra ohun-ìní ìdílé padà Rúùtù, ará Móábù sì wí pé, Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó sọ fún mi pé, Kí ń máa ṣa ọkà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ òun, títí wọn yóò fi parí ìkórè   Náómì sì sọ fún Rúùtù, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, Ìbá dára bí ó bá le bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́ Nítorí pé wọ́n le è dà ọ́ láàmú bí o bá lọ sí oko ẹlòmíràn Rúùtù sì bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin Bóásì ṣiṣẹ́ títí tí wọ́n fi parí ìkórè ọkà bálì àti ti jéró Ó sì ń gbé pẹ̀lú ìyá ọkọ rẹ̀ Rúùtù Àti Bóásì Ní Ilẹ̀ Ìpakà Ní ọjọ́ kan, Nóámì, ìyá ọkọ Rúùtù wí fún-un pé, Ọmọbìnrin mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí èmi bá ọ wá ilé ọkọ mìíràn fún ọ, níbi tí wọn yóò ti le è máa tọ́jú rẹ Wòó, Bóásì ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà ní ilẹ̀-ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí Wẹ̀, kí o sì fi ìpara-olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀-ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o sí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn síbi ẹsẹ̀ náà Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ Rúùtù sì fèsì pé, Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe Bẹ́ẹ̀ ni Rúùtù lọ sí ilẹ̀-ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún-un, pé kí o se Nígbà tí Bóásì parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀ Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà bálì tí wọ́n kó jọ Rúùtù yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó sí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀ Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárin òru, ẹ̀rú bàá, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀ Ó sì béèrè pé, Ta ni ìwọ í ṣe Rúùtù sì fèsì wí pé, Èmi ni Rúùtù, ìránṣẹ́-bìnrin rẹ Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà Bóásì sì wí fún-un pé, Kí Olúwa bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi Ìfẹ́ tí o fi hàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí talákà Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ìwọ ọmọbìnrin mi, má bẹ̀rù Èmi yóò sì ṣe ohun gbogbo tí o béèrè fún ọ Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ ọ́ ní obìnrin oníwà rere Nítòótọ́ ni wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó sún mọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó sún mọ́ ọ ju ti tèmi lọ Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí Olúwa ti ń bẹ láàyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́ Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n, ó dìde ní ìdájí kùtùkùtù kí ẹnìkín-ín-ní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀ Bóásì sì sọ fún-un wí pé, Má ṣe jẹ́ kí ó di mímọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀-ìpakà Ó sì tún wí fún-un pé, Mú aṣọ ìborùn rẹ tí o dà bora, kí o tẹ̀ ẹ sílẹ̀ Rúùtù sì ṣe bẹ́ẹ̀, Bóásì sì wọn òṣùwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà sí i, ó sì gbé e rù ú Nígbà náà ni ó padà sí ìgboro Nígbà tí Rúùtù dé ilé, Náómì, ìyá ọkọ sì bí léèrè pé, Báwo ni ó ti rí, ọmọbìnrin mi Nígbà náà ni ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún-un, fún ìyá ọkọ rẹ̀ Ó fi kún-un wí pé, Ó sọ fún mi wí pé, Má ṣe padà sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ ní ọwọ́ òfo, nítorí náà ó fún mi ní ìwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà   Náómì sì wí fún-un pé, Dúró, ọmọbìnrin mi títí tí ìwọ yóò fi mọ bí ohun gbogbo yóò ti rí Nítorí pé ọkùnrin náà kò ní sinmi títí tí ọ̀rọ̀ náà yóò fi yanjú lónìí Bóásì Gbé Rúùtù Ní Ìyàwó Nígbà náà ni Bóásì gòkè lọ sí ẹnu ìbodè ìlú, ó sì jòkòó síbẹ̀ Nígbà tí ìbátan tí ó sún mọ́ Elimélékì jùlọ, arákùnrin tí Bóásì ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọjá, Bóásì pè é wí pé, Máa bọ̀ wá síbí ìwọ ọ̀rẹ́ mi, kí o sì jokòó Ó sì lọ jokòó Bóásì sì pe mẹ́wàá nínú àwọn àgbààgbà ìlú, wí pé ki wọn jókòó, wọn sí se bẹ́ẹ̀, ó sì sọ fún ìbátan rẹ̀ náà pé, Arábìnrin Náómì tí ó dé láti ilẹ̀ Móábù fẹ́ ta ilẹ̀, èyí tí ó ṣe ti arákùnrin wa, Elimélékì Mó sì rò wí pé ó yẹ kí n mú ọ̀rọ̀ náà wá sí etí ìgbọ́ rẹ, wí pé kí o rà á ní iwájú gbogbo àwọn tí ó jòkòó sí ibi yìí Bí ìwọ yóò bá rà á padà, rà á Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ní rà á padà, sọ fún mi, kí èmi ó le è mọ̀ Nítorí pé kò sí ẹlòmíràn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á ju ìwọ lọ, èmi sì ni ẹni tí ó tún kàn lẹ́yìn rẹ̀ Ọkùnrin náà sì sọ wí pé, Èmi yóò rà á padà Nígbà náà ni, Bóásì sọ wí pé, Bí ìwọ bá ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Náómì àti lọ́wọ́ Rúùtù ará Móábù, ìwọ gbọdọ̀ fẹ opó ọkùnrin náà, kí orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà má ba à parẹ́ pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ àti kí o le è bímọ ní orúkọ rẹ̀ Nígbà náà ni ọkùnrin náà dáhùn sí èyí pé, Nípa ti èyí, èmi kò le rà á padà, nítorí pé, ọmọ rẹ, ọkùnrin yóò wá jẹ́ ajogún àwọn ohun-ìní mi pẹ̀lú Rà á fún ara rẹ, èmi kò le ṣe é Ní ayé ìgbà a nì, kí a tó le sọ wí pé ohun ìràpadà tàbí pàsípàrọ̀ ohun-ìní, fi ìdí múlẹ̀ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ẹnìkan ni láti yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi fún ẹnikejì, ó jẹ́ òfin fún ẹni tí ó fẹ́ rà á Nípa ṣíṣe èyí, àwọn ará Ísírẹ́lì fihàn wí pé ọ̀rọ̀ náà ti fìdímúlẹ̀ Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin náà sọ fún Bóásì wí pé, Ìwọ rà á fúnràrẹ, ó yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ Nígbà náà ni Bóásì wí fún àwọn àgbààgbà àti àwọn mìíràn tí ó wà ní ibẹ̀ pé, Gbogbo yín jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní òní wí pé mo ti ra ohun gbogbo tí í ṣe ti Elimélékì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì Málíónì àti Kílíónì lọ́wọ́ Náómì Ní àfikún, mo ra Rúùtù ará Móábù opó Málíónì padà láti di aya mi Èyí tí yóò mú kí orúkọ ọkùnrin òkú náà wà pẹ̀lú ohun-ìní rẹ̀, kí ìran rẹ̀ má ba à lè parẹ́ láàrin àwọn ẹbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀ Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ní òní Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ dáhùn wí pé, Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí, kí Olúwa jẹ́ kí obìnrin tí ó ń bọ̀ wá sí inú ilẹ̀ rẹ dàbí Rákélì àti Léà láti ara àwọn ẹni tí gbogbo ìdílé Ísírẹ́lì ti jáde wá Kí ìwọ sì di ọlọ́rọ̀ ní ìran Éfúráta àti olókìkí ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Kí Olúwa fún ọ ní ọmọ tí yóò mú ìdílé rẹ dàbí ti Pérésì, ọmọkùnrin tí Támárì bí fún Júdà láti ipaṣẹ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin yìí Báyìí ni Bóásì ṣe mú Rúùtù, tí ó sì di aya rẹ̀ Nígbà náà ni ó wọlé tọ aya rẹ̀, Olúwa sì mú kí ó lóyùn, ó sì bí ọmọ ọkùnrin kan Àwọn obìnrin sì wí fún Náómì pé, Ìyìn ni fún Olúwa tí kò fi ọ sílẹ̀ ní òní yìí láìní ìbátan, Olùràpadà Kí ọmọ náà di olókìkí ní Ísírẹ́lì Yóò tún ayé rẹ ṣe, yóò sì dáàbò bò ọ́ ní ọjọ́ ogbó rẹ Nítorí pé ìyàwó ọmọ rẹ, èyí tí ó sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ, tí ó sì fẹ́ràn rẹ ni ó bí ọmọ yìí fún Náómì sì gbé ọmọ náà lé orí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń tọ́jú rẹ̀ Àwọn obìnrin àdúgbò sì wí pé, A bí ọmọkùnrin kan fún Náómì Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Óbédì Òun sì ni baba Jésè tí í ṣe baba Dáfídì Èyí ni ìran Pérésì Pérésì ni baba Ésírónì, Ésírónì ni baba Rámú, Rámù ni baba Ámínádábù Ámínádábù ni baba Násónì, Násónì ni baba Sálímónì, Sálímónì ni baba Bóásì, Bóásì ni baba Óbédì, Óbédì ní baba Jésè, Jésè ni baba Dáfídì Olùfẹ́ Orin àwọn orin tí i ṣe orin Sólómónì Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde Abájọ tí àwọn wúndíá fi fẹ́ ọ Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá Ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀ Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́! Èmi dúdú mo sì ní ẹwà Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, Dúdú bí àgọ́ Kédárì Bí àgọ́ aṣọ kọ́tìnnì ti Sólómónì Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú Nítorí òòrùn mú mi dúdú Ọmọkùnrin ìyá mi bínú sími Ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà Ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú Ṣọ fún mi ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́, Níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán Kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin aṣán Ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ Bí ìwọ kò bá mọ̀, Ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin Bá ọ̀nà ti agbo ẹran rìn lọ Kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùsọ́ àgùntàn Olùfẹ́ mi, Mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Fáráò Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́, Ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀ A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ, A ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀ Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀ Òróró ìkunra mi tú òórùn jáde Ìdì òjíá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi Òun ó sinmi lé àárin ọmú mi Bí ìdì ìtàná Hénínà ni Olùfẹ́ mi rí sí mi Láti inú ọgbà àjàrà ti Énígédì Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olùfẹ́ mi! Áá à, Báwo ni o ṣe lẹ́wà tó! Ìwọ ní ojú ẹyẹlé Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi! Áá à, Báwo ni o ṣe wu ni! Ibùsùn wa ní ìtura Ìtànsán ilé wa jẹ́ ti igi kédárì Ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi Fírì Olùfẹ́ Èmi ni ìtànná Ṣárónì Bí ìtàná lílì àwọn àfonífojì Bí ìtànná lílì ní àárin ẹ̀gún ni olùfẹ́ mi ní àárin àwọn wúndíá Bí igi ápù láàrin àwọn igi inú igbó, ni olùfẹ́ mí láàrin àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀, Èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àṣè, Ìfẹ́ sì ni ọ̀pàgun rẹ̀ lórí mi Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró Fi èṣo ápù tù mi lára Nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí mi Ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú Kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè Kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi! Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀ Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá, Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kékèké Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé, Dìde, Olùfẹ́ mi, Arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi Wò ó! Ìgbà otútù ti kọjá Òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ Àwọn òdòdó fara hàn lórí ilẹ̀ Àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé A sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde Àwọn àjàrà nípa ìtànná wọn fún ni ní òórùn dídùn Dìde, wá, Olùfẹ́ mi Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta, ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga, fi ojú rẹ hàn mí, jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ Nítorí tí ohùn rẹ dùn, tí ojú rẹ sì ní ẹwà Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kékèké tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtàná Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀ Ó ń jẹ láàrin àwọn lílì Títí ìgbà ìtura ọjọ́ títí òjìji yóò fi fò lọ, yípadà, olùfẹ́ mi, kí o sì dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín lórí òkè Bétérì Ní orí ìbùsùn mi ní òru mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́ mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú, ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde Èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi Bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́ Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀ Ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́ Mo dì í mú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi, sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, Mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá bí ìkuku èéfín tí a ti fi òjíá àti tùràrí kùn lára pẹ̀lú gbogbo ètù olóòórùn oníṣòwò Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Sólómónì, Àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká, Àwọn akọni Ísírẹ́lì, Gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́, gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun, Idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru Sólómónì ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀ Ó fi igi Lébánónì ṣe é Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀ Ó fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀ Ó fi elésè àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀, Inú rẹ̀ ni ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù Ẹ jáde wá, ẹyin ọmọbìnrin Ṣíónì, kí ẹ sì wo ọba Sólómónì tí ó dé adé, Adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e Ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, Ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀ Olùfẹ́ Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olùfẹ́ mi! Áá à ìwọ jẹ́ arẹwà Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ Irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́ Tí ó sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè Gílíádì Ẹyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀ olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yàgàn Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó Ẹnu rẹ̀ dùn Èrẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pàmógíránéètì lábẹ́ ìbòjú rẹ Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dáfídì, tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún àpáta kọ́, gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára Ọmú rẹ méjèèjì dàbí ọmọ ẹgbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì tí ń jẹ láàrin ìtànná lílì Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀ tí òjìji yóò fi fò lọ, Èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjíá àti sí òkè kékeré tùràrí Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwa, olùfẹ́ mi kò sì sí àbàwọ́n lára rẹ Kí a lọ kúrò ní Lẹ́bánónì, ìyàwó mi, ki a lọ kúrò ní Lẹ́bánónì Àwa wò láti orí òkè Ámánà, láti orí òkè ti Ṣénírì, àti téńté Hérímónì, láti ibi ihò àwọn kìnnìún, láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi Ìwọ ti gba ọkàn mi pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ, pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ, Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi! Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ, òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ! Ètè rẹ ń kán dídùn afárá oyin, ìyàwó mi wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lébánónì Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábinrin mi, ìyàwó mi ìṣun tí a sé mọ́, oríṣun tí a fi èdìdì dì Ohun ọ̀gbìn rẹ àgbàlá pàmóńgánéètì ni ti òun ti àṣàyàn èso kípírésì àti nádì, Nádì àti Ṣáfírónì, kálámúsì àti kínámónì, àti gbogbo igi olóòórùn dídùn, òjíá àti álóé pẹ̀lú irú wọn Ìwọ ni ọgbà oríṣun, kànga omi ìyè, ìṣàn omi láti Lẹ́bánónì wá Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwá kí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúṣù! Fẹ́ lórí ọgbà mi, kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀ kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀ Olùfẹ́ Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi mo ti kó òjíá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu, àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́ Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí Gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ilẹ̀kùn Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi Orí mi kún fún omi ìrì, irun mi kún fún òtútù òru Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀ Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ilẹ̀kùn inú mi sì yọ́ sí i Èmi dìde láti sílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, òjíá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi, òjíá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń ṣàn sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn Èmi sí ilẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀ Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ ìlú rí mi bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká Wọ́n nà mí, wọ́n ṣá mi lọ́gbẹ́ wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, mo bẹ̀ yín bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi, kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un Ẹ wí fún un pé àìṣàn ìfẹ́ ń ṣe mi Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọ Ìwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọ tí ìwọ fi ń rọ̀ wá bẹ́ẹ̀ Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ ìdì ìrun rẹ̀ rí bí i ìmọ̀ ọ̀pẹ ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà ní ẹ̀bá odò tí ń ṣàn, tí a fi wàrà wẹ̀, tí ó jìn, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́ Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí ti ó sun òórùn tùràrí dídùn Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì ó ń kán òjíá olóòórùn dídùn Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà, tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán tí a fi Ṣáfírè ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ Ẹṣẹ̀ rẹ̀ rí bi i òpó mábù tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kédárì Lẹ́bánónì, tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́ Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀ ó wu ni pátapáta Áà! Ẹ̀yín ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, Èyí ní olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi Ọ̀rẹ́ Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ, Ìwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí, kí a lè bá ọ wá a Olùfẹ́ mi ti ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀, sí ibi ibùsùn tùràrí, láti máa jẹ nínú ọgbà láti kó ìtànná lílì jọ Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi, Ó ń jẹ láàárin ìtànná lílì, Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tírísà, Ìwọ lẹ́wà bí i Jérúsálẹ́mù, ìwọ lẹ́rù bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun Yí ojú rẹ kúrò lára mi nítorí ojú rẹ borí mi Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́ tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gílíádì Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn, Tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá, gbogbo wọn bí ìbejì, kò sì sí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bá ìbòjú rẹ, rí bí ẹ̀là èso pómégíránéètì Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀, àti ọgọ́rin àlè, àti àwọn wúndíá láìníye Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni, ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ, ààyò ẹyọkan ṣoṣo ẹni tí ó bí i Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún Àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fun-un Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀, tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí òòrùn, tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun Èmi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì, láti rí i bí àjàrà rúwé, tàbí bí pómégíránéètì ti rúdìí Kí èmi tó mọ̀, àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàárin àwọn ènìyàn mi Padà wá, padà wá, ìwọ Ṣúlámátì padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣúlámátì wò, bí ẹni pé orin ijo Máhánáímù Báwo ni ẹṣẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà, Ìwọ ọmọbìnrin ọba! Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́ iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà Ìdodo rẹ rí bí àwo tí kì í ṣe aláìní ọtí, ìbàdí rẹ bí òkìtì àlìkámà tí a fi lílì yíká Ọmú rẹ rí bí abo àgbọ̀nrín méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín-erin Ojú rẹ rí bí adágún ní Héṣébónì ní ẹ̀bá ẹnu ìbodè Bátírábímù Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lẹ́bánónì tí ó kọ ojú sí Dámásíkù Bí òkè kámẹlì ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká Bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́! Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ, àti ọmú rẹ bí idì èso àjàrà Mo ní, Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ Èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà, Àti èémi imú rẹ bí i ápù Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ Tí ó kúnná tí ó sì dùn, tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀ Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe, èmí sì ni ẹni tí ó wù ú Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá, Jẹ́ kí a lo àṣálẹ̀ ní àwọn ìletò Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù láti wo bí àjàrà rúwé bí ìtànná àjàrà bá là Àti bí póméegíránéètì bá ti rúdí, níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ Àwọn èṣo mánídárákì mú òórùn wọn jáde ní ẹnu ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso, èso ọ̀tún àti àkúgbó tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi Ọ̀rẹ́ Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin mi sí mi èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà! Èmi ìbá rí ọ ní òde, èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu, wọn kì bá fi mi ṣe ẹlẹ́yà Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́ èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyá mi, ìwọ ìbá kọ́ mi èmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòrùn dídùn fún ọ mu àti oje èso pómégíránéètì mi Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbá mí mọ́ra Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, èmi pè yín ní ìjà, Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè, Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti ihà, tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀ ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì bí èdìdì lé apá rẹ nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú, ìjowú sì le bí isà òkú jíjò rẹ̀ rí bí ìjò iná, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ iná Olúwa Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́, ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀, a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátapáta Àwa ní arábìnrin kékeré kan, òun kò sì ní ọmú, kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa, ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ Bí òun bá jẹ́ ògiri, Àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí Bí òun bá jẹ́ ilẹ̀kùn, Àwa yóò fi pákó kédárì dí i Èmi jẹ́ ògiri, ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́ bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀ bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá Sólómónì ní ọgbà àjàrà kan ní Báálí-Hómónì ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá ẹgbẹ̀rún fàdákà Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Sólómónì, igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ, Jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ! Yára wá, Olùfẹ́ mi, kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin, tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín, lórí òkè òórùn dídùn Iṣẹ́ Títù Sí Kírétè Pọ́ọ̀lù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti Àpósítélì Jésù Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, àti ìmọ̀ òtítọ́ irú èyí tí í máa darí ènìyàn sí ìgbé ayé ìwà bí Ọlọ́run— ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti se ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀, àti pé ní àkókò tirẹ̀, òun ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn nínú ìwàásù tí a fi lé mi lọ́wọ́ nípa àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa Sí Títù, ọmọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́ wa kan náà Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Kírísítì Jésù Olùgbàlà wa Ìdí tí mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè ni pé kí o lè ṣe àsepé àwọn iṣẹ́ tó sẹ́kù Mo sì ń rọ̀ ọ́ kí o yan àwọn alàgbà ní ìlú kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí mo ṣe darí rẹ̀ Ẹni tí yóò jẹ́ alàgbà gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onìyàwó kan, ọmọ wọn náà gbọdọ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí kò ní ẹ̀sùn ìwà ipá tàbí ẹ̀sùn àìgbọ́ràn kankan Alámójútó jẹ́ ẹni tí a gbé iṣẹ́ Ọlọ́run lé lọ́wọ́, nítorí náà, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kankan tàbí agbéraga, oníjà, kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí tàbí alágídí tàbí olójúkòkòrò Wọ́n ní láti jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, olùfẹ́ ohun tí ó dára Wọ́n ní láti jẹ́ ẹni tí ó kò ara rẹ̀ ní ìjánu, ẹni dúró sinsin, ọlọ́kàn mímọ́, àti ẹni oníwàtítọ́ Ó gbọdọ̀ di ẹ̀kọ́ nìpa ìdúrósinsin mú dáadáa gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ọ, kí ó lè fi ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro kọ́ àwọn ẹlòmíràn Nípa èyí, yóò lè fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀ fún àwọn alátakò Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ọlọ̀tẹ̀, afínnú àti ẹlẹ́tàn pàápàá jùlọ láàrin àwọn onílà Ó gbọdọ̀ pawọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí wí pé wọ́n ń pa agbo Ọlọ́run run, nípaṣẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí kò jẹ́ èyí tí wón ń kọ́ni Èyí ni wọ́n ń ṣe fún ere àìsòdodo Ọ̀kan nínú àwọn wòlíì wọn pàápàá sọ wí pé, òpùrọ́ ní àwọn ará Kírétè, wọ́n jẹ́ ẹranko búburú tí kò sé tù lójú, ọ̀lẹ, oníwọ̀ra Òtítọ́ ni ẹ̀rí yìí Nítorí náà, bá wọn wí gidigidi, kí wọn baà lè yè koro nínú ìgbàgbọ́ kí àwọn má ṣe fiyè sí ìtàn lásán ti àwọn Júù, àti òfin àwọn ènìyàn tí wọ́n yípadà kúrò nínú òtítọ́ Sí ọlọ́kàn mímọ́, ohun gbogbo ló jẹ́ mímọ́, ṣùgbọ́n àwọn tó ti díbàjẹ́ tí wọ́n kò sí ka ohunkóhun sí mímọ́ Nítòótọ́, ati ọkàn àti ẹ̀rí ọkàn wọn ló ti díbàjẹ́ Wọ́n ń fẹnu sọ wí pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ ẹ nípa ìṣe wọn Wọ́n díbàjẹ́, aláìgbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wúlò lọ́nàkọnà ní ti iṣẹ́ rere gbogbo Àwọn Èkọ́ Tí A Gbọ́dọ̀ Kọ́ Ní Onírúurú Àkójọpọ̀ Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro lórí ìgbé ayé onígbàgbọ́ tòótọ́ Kọ́ àwọn àgbà ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìrònú àti láti jẹ́ ẹni àpọ́nlé àti ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Wọn gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó jinlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, nínú ìfẹ́ àti nínú ìpamọ́ra Bákan náà, ni kí ó kọ́ àwọn àgbà obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ bí àátí gbé ìgbé-ayé ẹni-ọ̀wọ̀, wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ afọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ tàbí olùfẹ́ wáìnì mímú, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ olùkọ́ ohun rere Nípa èyí, wọ́n yóò lè máa kọ́ àwọn òdóbìnrin láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn, láti jẹ́ ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ọlọ́kàn mímọ́, kí wọ́n máa ṣe ojúse wọn nínú ilé, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onínú rere, kí wón sì máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọ́n, kí ẹnikẹ́ni máa baà sọ̀rọ̀ òdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Bákan náà, rọ àwọn ọ̀dọ́ ọkùnrin láti kó ara wọn ni ìjánu Nínú ohun gbogbo fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí alápẹẹrẹ ohun rere Nínú ẹ̀kọ́ rẹ fi apẹẹrẹ ìwà pípé hàn, ẹni tó kún ojú òsùnwọ̀n jẹ́ ẹni tó jáfáfà nínú ọ̀rọ̀ sísọ, ẹni tí kò see tanù, kí ojú kò lé tí àwọn alátakò rẹ̀ nígbà tí wón kò bá rí ohun búburú sọ nípa rẹ̀ Kọ́ àwọn ẹrú láti se ìgbọ́ran sí àwọn olówó wọn nínú ohun gbogbo, láti máa gbìyànjú láti tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kò gbọdọ̀ gbó olówó wọn lẹ́nu, wọn kò gbọdọ̀ jàwọ́n lólè ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí wón jẹ́ ẹni tó seé gbẹ́kẹ̀lé, kí wọn ó làkàkà ní gbogbo ọ̀nà láti jẹ́ kí ìkọ́ni nípa Ọlọ́run àti Olùgbàlà ní ìtumọ̀ rere Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó mú ìgbàlà wà ti fara hàn fún gbogbo ènìyàn Ó ń kọ́ wa láti sẹ́ àìwà-bí Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a gbé ìgbé ayé ìkóra-ẹni-ní-ìjánu, ìdúrósinsin àti ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsínsìnyìí, bí a ti ń wọ̀nà fún ìrètí tó ní bùkún, èyí ń ní ìfarahàn ògo Ọlọ́run wa tí ó tóbi àti Olùgbàlà wa Jésù Kírísìtì Ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa láti rà fún ìràpàda kúrò nínú ìwà búburú gbogbo àti kí ó sì le wẹ̀ àwọn ènìyàn kan mọ́ fún ara rẹ̀ fún iní ohun tìkara rẹ̀, àwọn tó ń ní ìtara fún iṣẹ́ rere Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni kí ìwọ kí ó máa kọ wọn Gba ni níyànjú kí ó sì máa fi gbogbo àṣẹ bániwí Máe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó gàn ọ́ Ṣíṣe Ohun Tí Ó Tọ̀nà Rán àwọn ènìyàn náà létí láti máa tẹríba fún ìjọba àti àwọn aláṣẹ Kí wọn ṣe ìgbọ́ràn nígbà gbogbo, kí wọn sì múra fún iṣẹ́ rere gbogbo Wọn kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ ẹnikẹ́ni ní ibi, kí wọn jẹ́ ẹni àlááfíà àti ẹni pípé, kí wọn sì máa gbé ìgbé-ayé ìwà tútù pẹ̀lú ènìyàn gbogbo Nígbà kan rí, àwa pàápàá jẹ́ opè àti aláìgbọ́ràn, àti tàn wá jẹ, a sè ti sọ wá di ẹrú fún onírúurú ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ àti adùn ayé À ń gbé ìgbé-ayé àrankan àti owú kíkorò, a jẹ́ ẹni ìríra, a sì ń kórira ọmọ ẹnìkejì wa pẹ̀lú Ṣùgbọ́n nígbà tí inú rere àti ìfẹ́ Ọlọ́run Olùgbàlà wa farahàn, Ó gbà wá là Kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí àwa ṣe nínú òdodo bí kò ṣe nítorí àánú rẹ̀ Ó gbà wá là, nípaṣẹ̀ ìwẹ̀nù àtúnbí àti ìsọdọ̀tun ti Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí tú lé wa lórí ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́ nípaṣẹ̀ Jésù Kírísítì Olùgbàlà wá Tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó jẹ́ wí pé lẹ́hìn tí a tí dáwa láre nípaṣẹ̀ oore-ọ̀fẹ́, kí a lè jẹ́ ajùmọ̀jogún ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí Mo sì fẹ́ kí ó ṣe ìtẹnumọ́ rẹ̀, kí àwọn tí wọ́n ti gbàgbọ́ nínú Olúwa le kíyèsí láti máa fi ara wọn jìn fún iṣẹ́ rere Nǹkan wọ̀nyìí dára, wọ́n sì jẹ èrè fún gbogbo ènìyàn Ṣùgbọ́n yẹra kúrò nínú àwọn ìbéèrè òmùgọ̀, àti ìtàn ìran, àti àríyànjiyàn àti ìjà nípa ti òfin, nítorí pé àwọn nǹkan báyìí jẹ́ aláìlérè àti asán Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ dá ìyapa sílẹ̀ láàrin yín, ẹ bá a wí lẹ́ẹ̀kínní àti lẹ́ẹ̀kejì Lẹ́yìn náà, ẹ má ṣe ní ohunkóhun íṣe pẹ̀lú rẹ̀ Kí ó dá ọ lójú wí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti yapa, ó jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀, ó sì dá ara rẹ̀ lẹ́ni Ní kété tí mo bá ti rán Àtémà tàbí Tíkíkù sí ọ, sa gbogbo ipá rẹ láti tòmíwá ní Níkópólì, nítorí mo ti pinnu láti lo ìgbà òtútù mi níbẹ̀ Sa gbogbo agbára rẹ láti ran Sénà agbẹjọ́rò àti Àpólò lọ́wọ́ nínú ìrìnàjò wọn Rí i dájú pé wọn ní ohun gbogbo tí wọn nílò Àwọn ènìyàn nílò láti kọ́ bí a tí ń fi ara ẹni jìn sí iṣẹ́ rere kí wọn baà le pèsè ohun kòsémánìí fún ara wọn, nípa èyí, wọn kì yóò jẹ́ aláìléso Gbogbo àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ mi kí ọ Bá mi kí àwọn tí ó fẹ́ wa nínú ìgbàgbọ́ Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú gbogbo yín Àmín Ìpè Láti Padà Sí Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ní osù kẹ́jọ ọdún kejì Ọba Dáríúsì, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekaráyà ọmọ Bérékáyà, ọmọ Ídò wòlíì pé Olúwa ti bínú sí àwọn baba ńlá yín Nítorí náà sọ fún àwọn ènìyàn Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ẹ padà sí Ọ̀dọ̀ mi, Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, èmi náà yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ẹ má dàbí àwọn baba yín, àwọn tí àwọn wòlíì ìṣáájú ti ké sí wí pé Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí Ẹ yípadà nísinsìnyìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, àti kúrò nínú ìwà búburú yín ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí ti èmi, ni Olúwa wí Àwọn baba yín, níbo ni wọ́n wà Àti àwọn wòlíì, wọn ha wà títí ayé Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pà ni àṣẹ fún àwọn ìrànsẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, Gẹ́gẹ́ bí Olúwa àwọn ọmọ ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa   Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sébátì, ní ọdún kejì Dáríúsì, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Sekaráyà, ọmọ Berekáyà ọmọ Idò wòlíì wá, pé, Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin púpa kan, òun sì dúró láàrin àwọn igi míritílì tí ó wà ní ibi òòji lẹ́yìn rẹ̀ si ni ẹ̀ṣin púpa, adíkálà, àti funfun gbé wà Nígbà náà ni mo wí pé, Kí ni wọ̀nyí Olúwa mi Ańgẹ́lì tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, Èmi ó fi ohun tí wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́ Ọkùnrin tí ó dúró láàrin àwọn igi míritílì sì dáhùn ó sì wí pé, Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé Wọ́n si dá ańgẹ́lì Olúwa tí ó dúró láàrin àwọn igi mirtílì náà lóhùn pé, Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti ríi pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà Nígbà náà ni ańgẹ́lì Olúwa náà dáhùn ó sì wí pé, Olúwa àwọn ọmọ ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jérúsálẹ́mù, àti fún àwọn ìlú ńlá Júdà, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá ańgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn Ańgẹ́lì ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, Ìwọ kígbé wí pé Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Èmi ń fi ìjowú ńlá jówú fún Jérúsálẹ́mù àti fún Síónì Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí o gbé jẹ́ẹ nítorí nígbà ti mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀ṣíwájú Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí Mo padà tọ Jérúsálẹ́mù wá pẹ̀lú àánú ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jérúsálẹ́mù Má a ké síbẹ̀ pé Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí A o máa fi ire kun ilú-ńlà mi ṣíbẹ̀ Olúwa yóò sì máa tu Síónì nínú ṣíbẹ̀, yóò sì yan Jérúsálẹ́mù ṣíbẹ̀   Mo si gbé oju sòkè, mo sì rí, sì kíyèsí i, ìwo mẹ́rin Mo sì sọ fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, Kí ni nǹkan wọ̀nyí Ó si dà mí lóhùn pé, Àwọn ìwo wọ̀nyí ni ó tí tú Júdà, Ísírélì, àti Jérúsálẹ́mù ká Olúwa sì fi alágbẹ̀dẹ mẹ́rin kan hàn mí Nígbà náà ni mo wí pé, Kí ni àwọn wọ̀nyí wá ṣe O sì sọ wí pé, Àwọn wọ̀nyí ni ìwo tí ó ti tú Júdà ká, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò fi gbé orí rẹ̀ sòkè Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí wá láti dẹ́rùbà wọ́n, láti lé ìwo àwọn orilẹ̀-èdè jáde, ti wọ́n gbé ìwo wọn sorí ilẹ̀ Júdà láti tú enìyàn rẹ̀ ká Ẹ bèèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ Olúwa Olúwa tí o dá mọ̀nàmọ́ná, tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn, fún olúkúlúkù koríko ní pápá Nítorí àwọn òrìṣà tí sọ̀rọ̀ asán, àwọn aláfọ̀ṣẹ sì tí rí èké, wọn sì tí rọ àlá èké wọ́n ń tu ni nínú láṣán, nítorí náà àwọn ènìyàn náà ṣáko lọ bí àgùntàn, a ṣẹ wọn níṣẹ̀ẹ́, nítorí Olùṣọ́àgùntàn kò sí Ìbínú mi ru sí àwọn darandaran, èmi o sì jẹ àwọn olórí níyà nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti bẹ agbo rẹ̀, ilé Júdà wò, yóò ṣi fi wọn ṣe ẹṣin rẹ̀ dáradára ní ogun Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni òkúta igun ilé ti jáde wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni igi-èèkàn àgọ́ tí wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrún ogun tí wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn akóniṣiṣẹ́ gbogbo tí wá Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrin alágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun, nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wọn, wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin Èmi o sì mú ilé Júdà ní agbára, èmi o sì gba ilé Jósẹ́fù là, èmi ó sì tún mú wọn padà nítorí mo tí ṣàánú fún wọn, ó sì dàbí ẹni pé èmi kò ì tìí ta wọ́n nù nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, èmi o sì gbọ́ ti wọn Éfúráímù yóò sì ṣe bí alágbára, ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí-wáìnì àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í, wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa Èmi ó kọ sí wọn, èmi ó sì ṣà wọ́n jọ nítorí èmi tí rà wọ́n padà wọn ó sì pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ń pọ̀ sí í rí Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn kákiri orílẹ̀-èdè ṣíbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jínjìn wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọn ó sì tún padà Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú, èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Áṣíríà èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gílíádì àti Lébánónì a a kì yóò sì rí àyè fún wọn bí ó ti yẹ Wọn yóò sì la òkun wàhálà já, yóò sì lu rírú omi nínú òkun, gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ, a ó sì rẹ ìgbéraga Áṣíríà ṣílẹ̀, ọ̀pá aládé Éjíbítì yóò sí lọ kúrò Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú Olúwa wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀, ni Olúwa wí Olùṣọ́ Àgùntàn Méjì Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lébánónì, kí iná bá lè jẹ igi Kédárì rẹ run, Pohùnréré-ẹkún, igi fírì nítorí igi Kédárì ṣubú, nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́ ṣunkún kíkorò ẹ̀yin igi óákù tí Básánì, nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀ Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn ògo wọn bàjẹ́ gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìún nítorí ògo Jódánì bàjẹ́ Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run mi wí Bọ́ ọ̀wọ́-ẹran àbọ́pa Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, Ìbùkún ni fún Olúwa , nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀! Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn Nítorí èmi kì yóò ṣàánú fún àwọn ara ilẹ̀ náà mọ́, ni Olúwa wí, Ṣí kíyèsí í, èmi yóò fi olúkúlúkù ènìyàn lé aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ ọba rẹ̀, wọn yóò sì fọ́ ilẹ̀ náà, èmi kì yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn Èmi yóò sì bọ́ ẹran àbọ́pa, àní ẹ̀yin òtòsì nínú ọ̀wọ́ ẹran Mo sì mu ọ̀pá méjì ṣọ́dọ̀ mo pè ọ̀kan ni Oore-ọ̀fẹ́, mo pè èkejì ni Àmùrè mo sì bọ́ ọ̀wọ́-ẹran náa Olùṣọ àgùntàn mẹ́ta ni mo sì gé kúrò ní oṣù kan Ọkàn mi sì kòrìíra wọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì kóríra mi Mo sì wí pé, Èmi kì yóò bọ́ yin èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀ Mo sì mu ọ̀pá mi, ti a ń pè ní Oore-ọ̀fẹ́, mo ṣẹ́ ẹ méjì, ki èmi bá lè da májẹ̀mu mi tí mo tí bá gbogbo àwọn ènìyàn náà dá Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòsì nínú ọ̀wọ́-ẹran náà ti o dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ Olúwa ni Mo sì wí fún wọn pé, Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó-ọ̀yà mi bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó-ọ̀yà mi Olúwa sì wí fún mi pé, Ṣọ ọ sí àpótí ìsúra! Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí Mo sì mu ọgbọ̀n owo fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìsúra ní ilé Olúwa Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrin Júdà àti láàrin Íṣírẹ́lì Olúwa sì wí fún mi pé, Tún mú ohun-èlò Olùṣọ́-àgùntàn búburú kan ṣọ́dọ̀ rẹ̀ Nítorí Èmi o gbé olùṣọ́-àgùntàn kan dídé ni ilẹ̀ náà, tí kí yóò bẹ àwọn tí ó ṣègbé wò, ti kì yóò sì wá èyí tí ó yapa tí kì yóò ṣe ìtọ́jú èyí tí a pa lára tàbí kí ó bọ́ àwọn tí ara wọn dá pépé Ṣùgbọ́n òun yóò jẹ ẹran èyi tí ó ni ọ̀rá, yóò sì fa èékánna wọn ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn aṣán náà, tí ó fi ọ̀wọ́-ẹran sílẹ́! Idà yóò ge apá rẹ̀ àti ojú ọ̀tún rẹ̀ apá rẹ̀ yóò gbẹ pátapáta, ojú ọ̀tún rẹ̀ yóò sì fọ́ pátapáta! A Ó Pa Àwọn Ọ̀ta Íṣírẹ́lì Run Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa fún Íṣírẹ́lì, ni Olúwa wí, ẹni tí ó na àwọn ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀, tí ó sì da ẹ̀mi ènìyàn tí ń bẹ ni inú rẹ̀ Kíyèsí í, èmi yóò ṣọ Jérúsálẹ́mù dí àgọ́ ìwárìrì sí gbogbo ènìyàn yíká, nígbà tí wọn yóò dó ti Júdà àti Jérúsálẹ́mù Ní ọjọ́ náà, nígbà tí gbogbo orilẹ̀-èdè ayé bá parapọ̀ sí i, ni èmi yóò sọ Jérúsálẹ́mù di ẹrù òkúta fún gbogbo ènìyàn gbogbo àwọn tí ó bá sì fi dẹ́rù pa ara wọn ni a ó ge sí wẹ́wẹ́, ní ọjọ́ náà, ni Olúwa wí, Ni èmi yóò fí ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un èmi yóò sì sí ojú mi sí ilé Júdà, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè Àti àwọn baálẹ̀ Júdà yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, Àwọn ara Jérúsálẹ́mù ni agbára mi nípa Olúwa Ọlọ́run wọn Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò se àwọn baálẹ̀ Júdà bí ààrò iná kan láàrin igi, àti bi ẹfúùfù iná láàrin ìtí wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì a ó sì tún máa gbé inú Jérúsálẹ́mù ní ipò rẹ̀ Olúwa pẹ̀lú yóò kọ́ tètè gba àgọ́ Júdà là ná, kí ògo ilé Dáfídì àti ògo àwọn ara Jérúsálẹ́mù má ba gbé ara wọn ga sí Júdà Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò dáàbò bò àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù ẹni tí ó bá sì ṣe àìlera nínú wọn ní ọjọ́ náà, yóò dàbí Dáfídì ilé Dáfídì yóò sì dàbí Ọlọ́run, bí ańgẹ́lì Olúwa níwájú wọn Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, èmi yóò wá láti pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí ó wá kọjú ìjà sí Jérúsálẹ́mù Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ ṣórí ilé Dáfídì àti sórí Jérúsálẹ́mù wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa sọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń sọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀ Ní ọjọ́ náà ni ẹkún, ńláńlá yóò wà ni Jérúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀fọ̀ Hádádì Rímónì ni àfonífojì Mégídónì Ilẹ̀ náà yóò ṣọ̀fọ̀, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ìdílé Dáfídì lọ́tọ̀ àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀ ìdílé Nátanì lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ́ Ìdílé Léfì lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀ ìdílé Ṣimei lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀ Gbogbo àwọn ìdílé tí o kù, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀ Ìwẹ̀nùmọ́ Kúrò Nínú Ẹ̀ṣẹ̀ Ní ọjọ́ náà isun kan yóò sí sílẹ̀ fún ilé Dáfídì àti fún àwọn ará Jérúsálẹ́mù, láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìmọ́ wọn Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ni èmi ó gé orúkọ àwọn òrìṣà kúrò ni ilẹ̀ náà, a kì yóò sì rántí wọn mọ́ àti pẹ̀lú èmi ó mú àwọn wòlíì èké àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ kọjá kúrò ni ilẹ̀ náà Yóò sì ṣe, nígbà tí ẹnìkan yóò ṣọtẹ́lẹ̀ ṣíbẹ̀, ni baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí ó bí í yóò wí fún un pé, Ìwọ ki yóò yè nítorí ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ èké ni orúkọ Olúwa Àti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí o bí í yóò gun un ni àgúnpa nígbà tí ó bá ṣọtẹ́lẹ̀ Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlúkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí ṣọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ Ṣùgbọ́n òun o wí pé, Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ Òun o sì dáhùn pé, Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi Díde, ìwọ idà, sí olùṣọ́-àgùntàn mi, àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn, àwọn àgùntàn a sì túká èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kékèké Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀, ni Olúwa wí, a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀ Èmi ó sì mú apá kẹ́ta náà la àárin iná, èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà, èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán góòlu wò wọn yóò sì pé orúkọ mi, èmi yóò sì dá wọn lóhùn èmi yóò wí pé, Àwọn ènìyàn mi ni, àwọn yóò sì wí pé, Olúwa ni Ọlọ́run wa   Kíyèsí i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀, a ó sì pín ìkógun rẹ̀ láàrin rẹ̀ Nítorí èmi ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí Jérúsálẹ́mù fún ogun a ó sì ko ìlú naà, a ó sì kó àwọn ilé, a ó sì ba àwọn obìnrin jẹ́, ààbọ̀ ìlú náà yóò lọ sí ìgbékùn, a kì yóò sì gé ìyókù àwọn ènìyàn náà kúrò ni ìlú náà Nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ, yóò sì bá àwọn orílẹ̀-èdè náa jà, gẹ́gẹ́ bí í ti ìjà ní ọjọ́ ogun Ẹṣẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Ólífì, tí ó wà níwájú Jérúsálẹ́mù ni ila-oòrùn, òkè Ólífì yóò sì làá sí méjì, sí ìhà ilà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrun, àfonífojì ńláńlá yóò wà ìdajì òké náà yóò sì sí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúṣù Ẹ̀yin ó sì ṣá sí àfonífojì àwọn òkè mi nítorí pé àfonífojì òkè náà yóò dé Àṣàlì nítòòtọ́, ẹ̀yin ó ṣá bí ẹ tí ṣá fún ìmímì-ilẹ̀ ni ọjọ́ Úṣáyà ọba Júdà Olúwa Ọlọ́run mi yóò sì wá, àti gbogbo àwọn Ẹni-mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ kì yóò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣókùnkùn Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ọjọ́ kan mímọ́ fún Olúwa , kì í ṣe ọ̀ṣán, kì í ṣe òru ṣùgbọ́n yóò ṣe pé, ni àṣálẹ́ ìmọ́lẹ̀ yóò wà Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jérúsálẹ́mù ṣàn lọ ìdájì wọn sìhà òkun ilà-oòrùn, àti ìdájì wọn síhà okùn ẹ̀yìn nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò sì jọba lórí gbogbo ayé ni ọjọ́ náà ni Olúwa kan yóò wa orúkọ rẹ̀ nìkan náà ni orúkọ A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Gébà dé Rímónì lápá gúsù Jérúsálẹ́mù yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jérúsálẹ́mù ṣókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Bẹ́ńjámínì títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ile ìṣọ́ Hánánélì dé ibi ìfúńtí wáìnì ọba Ènìyàn yóò sì máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ìparun mọ́ ṣùgbọ́n a o máa gbé Jérúsálẹ́mù láìléwu Èyí ni yóò sì jẹ́ àrùn tí Olúwa yóò fi kọlu gbogbo àwọn ènìyàn ti ó tí ba Jérúsálẹ́mù jà ẹran-ara wọn yóò rù nígbà tí wọn dúró ni ẹṣẹ̀ wọn, ojú wọn yóò sì rà ni ihò wọn, ahọ́n wọn yóò sì bàjẹ́ ni ẹnu wọn Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò wà láàrin wọn wọn ó sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ ìkínní yóò sì dìde sì ọwọ́ ìkejì rẹ̀ Júdà pẹ̀lú yóò sì jà ni Jérúsálẹ́mù ọrọ̀ gbogbo awọn aláìkọlà tí ó wà káàkiri ni a ó sì kójọ, góòlu, àti fàdákà, àti aṣọ, ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ Bẹ́ẹ̀ ni àrùn ẹṣin, ìbáákà, ràkúnmí, àti tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, yóò sì wà, àti gbogbo ẹranko tí ń bẹ nínú àgọ́ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àrùn yìí Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí o kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jérúsálẹ́mù yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sìn Ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti láti ṣe àjọyọ̀ àṣè àgọ́ náà Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí kì yóò gòkè wá nínú gbogbo ìdílé ayé sí Jérúsálẹ́mù láti sín Ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, òjò kì yóò rọ̀ fún wọn Bí ìdílé Éjíbítì kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò àrùn náà yóò wà, tí Olúwa yóò fi kọlù àwọn aláìkọlà tí kò gòkè wá láti se àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà Èyí ni yóò sì jẹ́ ìyà Éjíbítì, àti ìyà gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti pa àsè àgọ́ mọ́ Ní ọjọ́ náà ni MÍMỌ́ SÍ Olúwa yóò wà lára ṣaworo ẹṣin àti àwọn ìkòkò ni ilé Olúwa yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jérúsálẹ́mù àti ni Júdà yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun àti gbogbo àwọn tí ń rubọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kénánì kò ní sí mọ́ ni ile Olúwa àwọn ọmọ-ogun Okùn-Ìwọ̀n Ti Jérúsálẹ́mù Mó si tún gbé ojú mi, sòkè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ọkùnrin kan ti o mú okùn-ìwọ̀n lọ́wọ́ rẹ̀ Mo sí wí pé, Níbo ni ìwọ ń lọ O sí wí fún mí pé, Láti wọn Jérúsálẹ́mù, láti rí iyé ìbú rẹ̀, àti iyé gígùn rẹ̀ Sì kiyesí i, ańgẹ́li tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, ańgẹ́lì mìíràn si jáde lọ pade rẹ̀ Ó si wí fún un pé, Sáré, sọ fún ọdọmọkùnrin yìí wí pé, A ó gbé inú Jérúsálẹ́mù bi ìlú ti kò ní odi, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn àti ohun-ọ̀sìn inú rẹ̀ Olúwa wí pé, Èmí ó sì jẹ́ odi iná fún un yíká, èmi ó sì jẹ́ ògo láàrin rẹ̀ Áà! Áà! Sá kúrò ni ilẹ̀ àriwá, ni Olúwa wí nítorí pé bí afẹ́fẹ́ mẹ́rin ọ̀run ni mo tú yín kákiri, ni Olúwa wí Gbà ara rẹ̀ sílẹ̀, Ìwọ Síonì, ìwọ tí ó ń bà ọmọbìnrin Bábílónì gbé Nítorí bayìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Lẹ́yìn ògo rẹ̀ ni a ti rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń kó yin nítorí ẹni tí ó tọ́ yin, ó tọ́ ọmọ ojú rẹ̀ Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ikogun fún iránṣẹ́ wọn ẹ̀yín yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi Kọrin kí o sì yọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì Nítorí èmi ń bọ̀ àti pé èmi yóò sì gbé àárin rẹ, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò dàpọ̀ mọ́ Olúwa ní ọjọ́ náà, wọn yóò sì di ènìyàn mi èmi yóò sì gbé àárin rẹ, ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí ọ Olúwa yóò sì jogún Júdà ìní rẹ̀, ni ilẹ̀ mímọ́, yóò sì tún yan Jérúsálẹ́mù Ẹ̀ dákẹ̀, gbogbo ẹran-ara níwájú Olúwa nítorí a jí i láti ibùgbé mímọ́ rẹ̀ wá Asọ Mímọ́ Fún Olórí Àlùfáà Ó sì fí Jóṣúà olorí àlùfáà hàn mí, ó dúró níwájú ańgẹ́lì Olúwa , Sátanì sí dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti kọjú ìjà sí i Olúwa si wí fún Sátanì pé, Olúwa bá ọ wí ìwọ Sátanì àní Olúwa tí ó ti yan Jérúsálẹ́mù, yóò bá ọ wí, igi inà kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná A sì wọ Jóṣúà ni àṣọ èérí, ó sì dúró níwájú ańgẹ́lì náà Ó sì dáhùn ó wí fún àwọn tí ó dúró níwájú rẹ̀ pé, Bọ́ aṣọ èérí nì kúrò ní ara rẹ̀ Ó sì wí fún Jóṣúà pé, Wòó, mo mú kí àìṣedéédé rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, èmi yóò sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ ẹ̀yẹ Mó sì wí pé, Jẹ kí wọn fi gèlè mímọ́ wé e lórí Wọn si fi gèlè mímọ́ wé e lorí, wọn si fi aṣọ wọ̀ ọ́ Ańgẹ́lì Olúwa sì dúró tì í Ańgẹ́lì Olúwa sì tẹnumọ́ ọn fún Jóṣúà pé Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Bí ìwọ ọ́ bá rìn ní ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì pa àṣẹ mi mọ́, ìwọ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilé mi pẹ̀lú, ìwọ yóò sì ṣe àkóso ààfin mi, èmi yóò fún ọ ní àyè láti rìn láàrin àwọn tí ó dúró yìí Gbọ́, ìwọ Jóṣúà olórí àlùfáà, ìwọ, àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ tí ó jòkòó níwájú rẹ nítorí ẹni ìyanu ni wọ́n nítorí kíyèsí i, èmi yóò mú ìránṣẹ́ mi, Ẹ̀ka, wá Nítorí kíyèsí i, òkúta tí mo tí gbé kalẹ̀ níwájú Jóṣúà lórí òkúta kán ni ojú méje wà kíyèsí i, èmi yóò fín àkọlé rẹ̀, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan   Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ní ọjọ́ náà ni olúkúlùkù yóò pe ẹnìkejì láti jókòó rẹ̀ sábẹ́ igi àjàrà àti sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́   Ọ̀pá Fìtílà Wúrà Àti Àwọn Igi Ólífì Méjì Ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tún dé, ó sì jí mi, bí ọkùnrin tí a jí lójú oorun rẹ̀, Ó sì wí fún mi pé, Kí ni ìwọ rí Mo sì wí pé, Mo wò, sì kíyèsí i, ọ̀pá fìtílà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò rẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú fìtílà méje rẹ̀ lórí rẹ̀, àti ẹnu méje fún fìtílà méjèèje, tí ó wà lórí rẹ̀ Igi ólífì méjì sì wà létí rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwokòtò náà, àti èkejì ní apá òsì rẹ̀ Mo sì dáhùn mo sì wí fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, Kín ni wọ̀nyí, Olúwa mi Ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí Mo sì wí pé, Èmi kò mọ̀ ọ́n, Olúwa mi Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubábélì tó wí pé Kìí ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò se nípa Ẹ̀mí mi, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubábélì òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, Ọlọ́run bùkún-un Ọlọ́run bùkún-un!  Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé Ọwọ́ Serubábélì ni a ti ṣe ipilẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀ ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré Nítorí wọn ó yọ̀ ní, ìwọ̀n lọ́wọ́ Serubábélì Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, Kí ni àwọn igi ólífì méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀ Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí Mo sì wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa à mi Ó sì wí pé, Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé Ìwé-Kíkà Ti Ń Fò Nígbà náà ni mo yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsí i, ìwé-kíkà ti ń fò Ó sì wí fún mi pé, Kí ni ìwọ rí Èmi sì dáhùn pé, Mo rí ìwé-kíkà tí ń fò gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá Ó sì wí fún mi pé, Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó gèé kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀ gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó gèé kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀ Èmi o mú un jáde, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi ọrúkọ mi búra èké yóò si wà ni àárin ilé rẹ̀, yóò si rún un pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀   Ańgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì jáde lọ, ó sì wí fún mi pé, Gbé ojú rẹ sókè níṣinṣin yìí, kí o sì wo nǹkan yìí tí ó jáde lọ Mo sì wí pé, Kí ni nǹkan náà Ó sì wí pé, Èyí ni òṣùwọ̀n éfà tí ó jáde lọ Ó sì wí pé, Èyí ni àwòrán ní gbogbo ilẹ̀ ayé Sì kíyèsí i, a gbé talẹ́ńtì òjé sókè obìnrin kan sì nìyìí tí ó jókòó sí àárin òṣùwọ̀n éfà Ó sì wí pé, Èyí ni ìwà-búburú Ó sì jù ú sí àárin òṣùwọ̀n éfà ó sì ju òṣùwọ̀n òjé sí ẹnu rẹ̀ Mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsí i, obìnrin méjì jáde wá, èfúùfù sì wá nínú ìyẹ́ wọn nítorí wọ́n ní ìyẹ́ bí ìyẹ́ àkọ̀ Wọ́n sì gbé òṣùwọ̀n éfà náà dé àárin méjì ayé àti ọ̀run Mo sì sọ fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, Níbo ni àwọn wọ̀nyí ń gbé òṣùwọ̀n éfà náà lọ Ó si wí fún mi pé, Sí orílẹ̀ èdè Bábílónì láti kọ ilé fún un Tí ó bá ṣe tán, a ó sì fi ìdí rẹ̀ mulẹ̀, a o sì fi ka orí ìpìlẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀ Kẹ̀kẹ́ Ogun Mẹ́rin Tí Ìdàjọ́ Ọlọ́run Mo sì yípadà, mo sì gbé ojú mi sòkè, mo sì wò, sì kíyèsi i, kẹ̀kẹ́ mẹ́rin jáde wá láti àárin òkè-ńlá méjì, àwọn òkè-ńlà náà sì jẹ́ òkè-ńlà idẹ Àwọn ẹṣin pupa wà ní kẹ̀kẹ́ èkínní àti àwọn ẹṣin dúdú ní kẹ̀kẹ́ èkejì Àti àwọn ẹṣin funfun ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹta àti àwọn adíkálà àti alágbára ẹṣin ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹrin Mo sì dáhùn, mo sì béèrè lọ́wọ́ ańgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, Kí ni ìwọ̀nyí, Olúwa mi Ańgẹ́lì náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé Àwọn ẹṣin dúdú tí ó wà nínú rẹ̀ jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá àwọn funfun sì jáde tẹ̀lé wọn àwọn adíkálà sì jáde lọ sí ìhà ilẹ̀ gúsù Àwọn alágbára ẹṣin sì jáde lọ, wọ́n sì ń wá ọ̀nà àti lọ kí wọn báa lè rìn síhín-sọ́hùnún ni ayé ó sì wí pé, Ẹ lọ, ẹ lọ rìn síhìn-sọ́hùn ní ayé! Wọ́n sì rín síhìnín-sọ́hùnún ní ayé Nígbà náà ni ohùn kan sì ké sí mi, ó sì bá mi sọ̀rọ̀ wí pé, Wò ó, àwọn wọ̀nyí tí ó lọ síhà ilẹ̀ àríwá ti mú ẹ̀mí mi parọ́rọ́ ni ilẹ̀ àríwá Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé Mú nínú ìgbèkùn, nínú àwọn Hélídáì, tí Tóbíyà, àti ti Jédáyà, tí ó ti Bábílónì dé, kí ìwọ sì wá ní ọjọ́ kan náà, kí o sì wọ ilé Jósáyà ọmọ Séfánáyà lọ Kí o sì mú sílifà àti wúrà, kí o sì fi ṣe adé púpọ̀, sì gbé wọn ka orí Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà Sì sọ fún un pé Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogún sọ wí pé, wo ọkùnrin náà ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka yóò sì yọ ẹ̀ka láti abẹ́ rẹ̀ wá, yóò si kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa wa Òun ni yóò sì kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa òun ni yóò sì wọ̀ ní ògo, yóò sì jókòó, yóò sì jọba lorí ìtẹ́ rẹ̀ òun ó sì jẹ́ àlùfáà lorí ìtẹ́ rẹ̀ ìmọ̀ àlàáfíà yóò sì wá láàrin àwọn méjèèje Adé wọ̀nyí yóò sì wà fún Hélémù àti fún Tóbíyà, àti fún Jédíà, àti fún Hénì ọmọ Sefanáyà fún irántí ni tẹ́ḿpìlì Olúwa Àwọn tí ó jìnnà réré yóò wá láti kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa , ẹ̀yiń o sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rán mi sí yín Yóò sì rí bẹ́ẹ̀ bí ẹ̀yín o bá gbà ohùn Olúwa , Ọlọ́run yín gbọ́ nítootọ́ Òdodo Àti Àánú, Kì í Ṣe Ààwẹ̀ Ó sì ṣe ní ọdún kẹrin Dáríúsì ọba, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ Sekaráyà wá ni ọjọ́ kẹrin oṣù Kísíléfì tí ń se oṣù kẹsàn-án Nígbà tí wọ́n rán Sérésérì àti Régémélékì, àti àwọn ènìyàn wọn sí ilé Ọlọ́run láti wá ojú rere Olúwa Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù kárùnún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tọ̀ mí wá pé, Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti fún àwọn àlùfáà pé, Nígbà tí ẹ̀yin gbààwẹ̀, tí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karùnún àti keje, àní fun àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, ǹjẹ́ èmi ni ẹ̀yin hà ń gbààwẹ̀ yín fún Nígbà tí ẹ sì jẹ, àti nígbà tí ẹ mu, fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin jẹ, àti fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin mú bí Wọ̀nyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ ti Olúwa ti kígbe láti ọdọ àwọn wòlíì ìṣáájú wá, nígbà tí a ń gbé Jérúsálẹ́mù, tí ó sì wà ní àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ tí ó yí i káàkiri, nígbà tí a ń gbé gúsù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀   Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sekaráyà wá, wí pé Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti iyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀ Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tàlákà kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbérò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀ Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́ Wọ́n sé àyà wọn bí òkúta ádámáńtì, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ ogun wá  Ó sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti kígbe, tí wọn kò sì fẹ́ gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kígbe, tí èmi kò sì fẹ́ gbọ́, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀ Ilẹ̀ náà sì dáhoro lẹ́yìn wọn, tí ẹnikẹ́ni kò là á kọjà tàbí kí ó padà bọ̀ wọ́n sì sọ ilẹ̀ ààyò náà dáhoro   Ọlọ́run Ṣe Ìpinnu Láti Bùkún Jérúsálẹ́mù Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá, wí pé, Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Owú ńlá-ńlá ni mo jẹ fún Síónì, pẹ̀lú ìbínú ńlá-ńlá ni mo fi jowú fún un Báyìí ni Olúwa wí Mo yípadà sí Síónì èmi ó sì gbé àárin Jérúsálẹ́mù Nígbà náà ni a ó sì pé Jérúsálẹ́mù ni ìlú ńlá otítọ́ àti òkè-ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè-ńlá mímọ́ Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jérúsálẹ́mù, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdé-bìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé Bí ó bá ṣe ìyanú ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyánú ni ojú mi bí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé Kiyesi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárin Jérúsálẹ́mù wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹ́ḿpìlì Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olukuluku kọ aládùúgbò rẹ̀ Ṣùgbọ́n ní ìṣinṣinyìí èmi kì yóò ṣè sí ìyókù àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bí tí ìgbà àtijọ́, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Nítorí irúgbìn yóò gbilẹ̀ àjàrà yóò ṣo èṣo rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mu ìrì wọn wá èmi ó sì mu kí èyí jẹ ogún ìní àwọn ìyókù ènìyàn yìí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí Yóò ṣi ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrin àwọn aláìkọlà, ẹ̀yin ilé Júdà, àti ilé Íṣrẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀ ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí Gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣe yín níbi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, tí èmi kò sì ronúpìwàdà Bẹ́ẹ̀ ni èmi ṣí tí ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jérúsálẹ́mù, àti fún ilé Júdà ẹ má bẹ̀rù Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe Ẹ ṣọ̀rọ̀ òtítọ́, olúkúlúkù sí ẹnikejì rẹ̀ ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkeji rẹ̀ ẹ má fẹ ìbúra èké nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra, ni Olúwa wí Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé Ààwẹ̀ oṣù kẹrin, ìkárun-un, kéje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀, àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Júdà nítorí náà, ẹ fẹ́ otítọ́ àti àlàáfíà Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé Àwọn ènìyàn yóò ṣa tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú-ńlá púpọ̀ Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú-ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojú rere Olúwa , àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ Nítòótọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní Jérúsálẹ́mù àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojú rere Olúwa Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ   Ìdájọ́ Lórí Àwọn Ọ̀tá Ísírẹ́lì Ọ̀rọ̀ Olúwa kọjú ìjà sí Hádírákì, Dámásíkù ni yóò sì jẹ́ ibi ìṣinmi rẹ̀ nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára ènìyàn, àti lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì Àti Hámátì pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀ Tírè àti Sídónì bí o tilẹ̀ ṣe ọlọgbọ́n gidigidi Tírè sì mọ odi líle fún ara rẹ̀, ó sì kó fàdákà jọ bí èkuru, àti wúrà dáradára bí àfọ̀ ẹ̀rẹ̀ ìgboro Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ, yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú òkun, a ó sì fi iná jó o run Ásíkélónì yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù Gásà pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káànú gidigidi, àti Ékírónì nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò sákì í Gásà yóò pàdánu ọba rẹ̀, Ásíkélónì yóò sì di ahoro Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Ásídódì, Èmi yóò sì ge ìgbéraga àwọn Fílístínì kúrò Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀, àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrin eyín rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn tó sẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa, wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Júdà, àti Ékírónì ni yóò rí bí Jébúṣì Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi ká nítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri, kò sí aninilára tí yóò là wọ́n já mọ́ nítorí ni ìṣinṣin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn Ẹ kún fún ayọ̀, ẹ̀yin ọmọbìnrin Ṣíónì Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù Ẹ wo ọba yín ń bọ̀ wá ṣọ́dọ̀ yín òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Éfúráímù, àti ẹṣin ogun kúrò ni Jérúsálẹ́mù, a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn aláìkọlà Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti òkun dé òkun, àti láti odò títí de òpin ayé Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mu mi pẹ̀lú rẹ, Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ìrètí àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́poméjì Èmi ó fa Júdà le bí mo ṣe fa ọrun mi le, mo sì fi Éfúráímù kún un, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Ṣíónì, sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Gíríkì, mo ṣe ọ́ bí idà alágbára Olúwa yóò sì fí arahàn ní orí wọn Ọ̀kọ̀ rẹ̀ yóò tàn bí mọ̀nàmọ́ná Olúwa ọ̀gá-ògo yóò sì fọn ìpè, Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúṣù Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n wọn ó sì jẹ ni run, wọn ó sì tẹ òkúta kànnà-kànnà mọ́lẹ̀ wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì, wọn ó sì kún bí ọpọ́n, wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà bí agbo ènìyàn rẹ̀ nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé, tí a gbé sókè bí àmì lórí ilẹ̀ rẹ̀ Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ ṣi tí pọ̀! Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá, ati ọtí-wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ìkìlọ̀ fún Ìparun tí ń bọ̀ Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Sefanáyà ọmọ Kúsì, ọmọ Gédálíyà, ọmọ Ámáríyà, ọmọ Heṣekáyà, ní ìgbà Jósíà ọmọ Ámónì ọba Júdà Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúrò lórí ilẹ̀ náà pátapáta, ni Olúwa wí Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko kúrò èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run kúrò àti ẹja inú òkun, àti ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ni Olúwa wí Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Júdà àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín-yìí ìyókù àwọn Báálì, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà, àti àwọn tí wọn ń foríbalẹ̀ tí wọn ń sin ogun ọ̀run lórí òrùlé Àwọn tí wọn ń sìn, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra, tí wọ́n sì ń fi Mólékì búra Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Àti àwọn tí kò tí wá Olúwa , bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀ Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run, nítorí tí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀ Olúwa ti pèṣè ẹbọ kan sílẹ̀, ó sì ti ya àwọn alápèjẹ rẹ̀ sí mímọ́ Ní ọjọ́ ẹbọ Olúwa , Èmi yóò bẹ àwọn olórí wò, àti àwọn ọmọ ọba ọkùnrin, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wọ àjèjì aṣọ Ní ọjọ́ náà, èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí ó yẹra láti rìn lórí ìloro ẹnu ọ̀nà, tí wọ́n sì kún tẹ́ḿpìlì Olúwa wọn pẹ̀lú ìwà-ipá àti ẹ̀tàn Ní sì ṣe ní ọjọ́ náà, ni Olúwa wí, Ohùn ẹkún yóò wà láti ìhà Ibodè ẹja, híhu láti ìhà kejì wá àti ariwo ńlá láti òkè kékeré wá Hu, ẹ̀yin tí ń gbé ní agbègbè ọjà, gbogbo àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni a ó mú kúrò, gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ra fàdákà ni a ó sì parun Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jérúsálẹ́mù kiri pẹ̀lú fìtílà, èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn, tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn, àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kan tí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógún, àti ilé wọn yóò sì run Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbé nínú ilé náà, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtí Wáìnì láti inú rẹ̀ Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀ kánkán Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkún àwọn alágbára ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀, ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú, ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú, ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoro ọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba, ọjọ́ kuru àti òkùnkùn biribiri, ọjọ́ òpè àti ìdágìrì àti ìdágiri sí àwọn ìlú olódì àti sí àwọn ìsá gíga Èmi yóò sì mú ìpọ́njú wá sórí ènìyàn, wọn yóò sì máa rìn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú, nítorí àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí eruku àti ẹran-ara wọn bí ìgbẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọn kì yóò sì le gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú Olúwa Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi iná ìjowú rẹ̀ parun, nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sí gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé ayé Ìlòdì Sí Fílísítíà Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, àní ẹ kó ra yín jọpọ̀ orílẹ̀ èdè tí kò ní ìtìjú, kí a tó lé yín kúrò bí èrò ìyàngbò ọkà, kí gbígbóná ìbínú Olúwa tó dé bá a yín, kí ọjọ́ ìbínú Olúwa kí ó tó dé bá a yín Ẹ wá Olúwa , gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ń ṣe ohun tí ó bá pa láṣẹ Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú, bóyá á ó pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa Nítorí pé, a ó kọ Gásà sílẹ̀, Áṣíkélónì yóò sì dahoro Ní ọ̀sán gangan ni a ó lé Áṣídódù jáde, a ó sì fa Ékírónì tu kúrò Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun, ẹ̀yin ènìyàn ara Kérétì Ọ̀rọ̀ Olúwa dojúkọ ọ́, ìwọ Kénánì, ilẹ̀ àwọn ara Fílísítíà Èmi yóò pa yín run, ẹnìkan kò sì ní ṣẹ́kù nínú yín Ilẹ̀ náà ní etí òkun, ni ibùgbé àwọn ará Kérétì, ni yóò jẹ́ ibùjókòó fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti agbo àgùntàn Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Júdà, níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí ìjẹ fún ẹran, Ní ilé Áṣíkélónì ni wọn yóò dùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́ Olúwa Ọlọ́run wọn yóò bojútó wọn, yóò sì yí ìgbékùn wọn padà Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Móábù, àti ẹlẹ́yà àwọn Ámónì, àwọn tó kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn Nítorí náà, bí Èmi tí wà, ni Olúwa Sódómù wí, Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì, Ní tòótọ́ Móábù yóò dàbí Sódómù àti Ámónì yóò sì dàbí Gòmórà, ibi tí ó kún fún yèrèpè àti ihó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé Ìyòókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi ni yóò jogún ilẹ̀ wọn Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn, nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa alágbára ṣe ẹlẹ́yà Olúwa yóò jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn nígbà tí Òun bá pa gbogbo òrìṣa ilẹ̀ náà run Orílẹ̀-èdè láti etí odò yóò máa sìn, olúkúlùkù láti ilẹ̀ rẹ̀ wá Ẹ̀yin Etiópíà pẹ̀lú, a ó fi idà mi pa yín Òun yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ sí apá àríwá, yóò sì pa Ásíríà run, yóò sì sọ Nínéfè di ahoro, àti di gbígbẹ bí ihà Agbo ẹran yóò sì dùbúlẹ̀ ṣíbẹ̀ àti gbogbo ẹ̀dá ní orísìírísìí Òwìwí ihà àti dídún bí ẹyẹ òwìwí yóò wọ bí ẹyẹ ni ọwọ́n rẹ̀ Ohùn wọn yóò kọrin ni ojú fèrèsé, ìdahoro yóò wà nínú ìloro ẹnu ọ̀nà, òun yóò sì ṣẹ́ kédárì sílẹ̀ Èyí ni ìlú aláyọ̀ tí ó ń gbé láìléwu Ó sì sọ sí ara rẹ̀ pé, Èmi ni, kò sì sí ẹnìkan tí ó ń bẹ lẹ́yìn mi Irú ahoro wo ni òun ha ti jẹ́, ibùgbé fún àwọn ẹranko igbó! Gbogbo ẹni tí ó bá kọjá ọ̀dọ̀ rẹ̀ yóò fi rẹ́rìnín ẹlẹ́yà, wọ́n yóò sì gbọn ẹsẹ̀ wọn Ọjọ́ Ìwájú Jérúsálẹ́mù Ègbé ni fún ìlú aninilára, ọlọ̀tẹ̀ àti aláìmọ́ Òun kò gbọ́ràn sí ẹnikẹ́ni, òun kò gba ìtọ́ni, òun kò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa , bẹ́ẹ̀ ni òun kò súnmọ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀ Àwọn olórí rẹ̀ jẹ́ kìnnìun tí ń ké ramúramù, àwọn onídàájọ́ rẹ̀, ìkokò àṣálẹ́ ni wọn, wọn kò sì fi nǹkan kan kalẹ̀ fún òwúrọ̀ Àwọn wòlíì rẹ̀ gbéraga, wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti ba ibi mímọ́ jẹ́, wọ́n sì rú òfin Olúwa ni àárin rẹ̀ jẹ́ olódodo kì yóò ṣe ohun tí kò tọ̀nà Àràárọ̀ ni ó máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sí ìmọ́lẹ̀, kì í sì kùnà ní gbogbo ọjọ́ tuntun, ṣíbẹ̀ àwọn aláìsòótọ́ kò mọ ìtìjú Èmi ti ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, ilé gíga wọn sì ti bàjẹ́ Mo ti fi ìgboro wọn sílẹ̀ ní ihà tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnìkan kan kò kọjá níbẹ̀ Ìlú wọn parun tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnikan tí yóò sẹ́kù, kò sì ní sí ẹnìkan rárá Èmi wí fún ìlú náà wí pé Nítòótọ́, ìwọ yóò bẹ̀rù mi, ìwọ yóò sì gba ìtọ́ni! Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò ké ibùgbé rẹ̀ kúrò bí ó ti wù kí ń jẹ wọ́n níyà tó Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ wọ́n sì tún ní ìtara láti ba iṣẹ́ wọn jẹ́ Nítorí náà ẹ dúró dèmi, ni Olúwa wí, títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò dìde si ohun ọdẹ nítorí ìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ kí èmi kí ó lè kó ilẹ̀ ọba jọ àti láti rú ìbínú jáde sórí wọn, àní gbogbo ibínú gbígbóná mi Nítorí, a ó fi iná owú ibínú jẹ gbogbo ayé run Nígbà náà ni èmi yóò yí èdè àwọn ènìyàn padà sí èdè mímọ́, nítorí kí gbogbo wọn bá a lè máa pe orúkọ Olúwa , láti fi ọkàn kan sìnín Láti òkè odò Etiópíà, àwọn olùsìn mi, àwọn ènìyàn mi tí ó ti fọ́nká, yóò mú ọrẹ wá fún mi Ní ọjọ́ náà ni a kì yóò sì dójútì nítorí gbogbo ìsẹ́ni tí ó ti ṣe sí mi, nígbà náà ni èmi yóò mu kúrò nínú ìlú yìí, àwọn tí ń yọ̀ nínú ìgbéraga wọn Ìwọ kì yóò sì gbéraga mọ́ ní òkè mímọ́ mi Ṣùgbọ́n Èmi yóò fi àwọn ọlọ́kàn tútù àti onírẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ni àárin rẹ̀, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Àwọn ìyókù Ísírẹ́lì kì yóò hùwà ibi, wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè ní ẹnu wọn Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rù bà wọ́n Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Síónì, kígbé sókè, ìwọ Ísírẹ́lì! Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn, ìwọ ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì kúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀ta rẹ padà sẹ́yìn Olúwa , ọba Ísírẹ́lì wà pẹ̀lú rẹ, Ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́ Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jérúsálẹ́mù pé, Má ṣe bẹ̀rù Síónì má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀ Yóò tún ọ se nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ̀ fún àjọ mímọ́ jọ, àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀ àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù Ní àkókò náà ni èmi yóò dojúkọ àwọn tí ń ni yín lára, èmi yóò gba atiro là, èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ, èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n Ní àkókò náà ni èmi yóò ṣà yín jọ Nígbà náà ni èmi yóò mú un yín padà wá sílé Èmi yóò fi ọlá àti ìyìn fún un yín láàárin gbogbo ènìyàn àgbáyé, nígbà tí èmi yóò yí ìgbèkùn yín padà bọ sípò ní ojú ara yín, ni Olúwa wí