Lẹsẹkẹsẹ, ọmọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀lé e,bíi mààlúù tí wọn ń fà lọ pa,tabi bí àgbọ̀nrín tí ó tẹsẹ̀ bọ tàkúté, títí tí ọfà fi wọ̀ ọ́ ninubí ẹyẹ tí ń yára bọ́ sinu okùn,láì mọ̀ pé ó lè ṣe ikú pa òun. Nisinsinyii, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi,ẹ farabalẹ̀ gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín lọ sọ́dọ̀ irú obinrin bẹ́ẹ̀,ẹ má ṣèèṣì yà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ó ti sọ di ẹni ilẹ̀,ọpọlọpọ àwọn alágbára ni ó ti ṣe ikú pa. Ọ̀nà isà òkú tààrà ni ilé rẹ̀,ilé rẹ̀ ni ọ̀nà àbùjá sí ìparun. wé wọn mọ́ ìka rẹ,kí o sì kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ. Sọ fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arabinrin mi,”kí o sì pe ìmọ̀ ní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ, kí wọ́n baà lè pa ọ́ mọ́,kúrò lọ́dọ̀ alágbèrè obinrin,ati kúrò lọ́wọ́ onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀. Mo yọjú wo ìta,láti ojú fèrèsé ilé mi. Mo rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní ìrírí,mo ṣe akiyesi pé láàrin wọn,ọmọkunrin kan wà tí kò gbọ́n. Ó ń lọ ní òpópónà, lẹ́bàá kọ̀rọ̀ ilé alágbèrè obinrin náà, ní àṣáálẹ́, nígbà tí ọjọ́ ń pofírí,tí ilẹ̀ ti ń ṣú, tí òkùnkùn ti ń kùn. Yíyin Ọgbọ́n. Ọgbọ́n ń pe eniyan,òye ń pariwo. Gba ẹ̀kọ́ mi dípò fadaka,ati ìmọ̀ dípò ojúlówó wúrà, nítorí ọgbọ́n níye lórí ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ,kò sí ohun tí o fẹ́, tí a lè fi wé e. Èmi, ọgbọ́n, òye ni mò ń bá gbélé,mo ṣe àwárí ìmọ̀ ati làákàyè. Ẹni tó bá bẹ̀rù OLUWA, yóo kórìíra ibi,mo kórìíra ìwà ìgbéraga, ọ̀nà ibi ati ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́. Èmi ni mo ní ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n tí ó yè kooro,mo sì ní òye ati agbára. Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọba fi ń ṣe ìjọba,tí àwọn alákòóso sì ń pàṣẹ òdodo. Nípasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣe àkóso,gbogbo àwọn ọlọ́lá sì ń ṣe àkóso ayé. Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi,àwọn tí wọ́n bá fi tọkàntọkàn wá mi yóo sì rí mi. Ọrọ̀ ati iyì wà níkàáwọ́ mi,ọrọ̀ tíí tọ́jọ́, ati ibukun. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ,àyọrísí mi sì dára ju ojúlówó fadaka lọ. Ó dúró ní ibi tí ó ga lẹ́bàá ọ̀nà,ati ní ojú ọ̀nà tóóró, Ọ̀nà òdodo ni èmi ń rìn,ojú ọ̀nà tí ó tọ́ ni mò ń tọ̀. Èmi a máa fún àwọn tí wọ́n fẹ́ mi ní ọrọ̀,n óo máa mú kí ìṣúra wọn kún. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀. Láti ayébáyé ni a ti yàn mí,láti ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé rárá. Kí ibú omi tó wà ni mo ti wà,nígbà tí kò tíì sí àwọn orísun omi. Kí á tó dá àwọn òkè ńlá sí ààyè wọn,kí àwọn òkè kéékèèké tó wà, ni mo ti wà. Kí Ọlọrun tó dá ayé, ati pápá oko,kí ó tó dá erùpẹ̀ ilẹ̀. Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó dá ojú ọ̀run sí ààyè rẹ̀,tí ó ṣe àmì bìrìkìtì sórí ibú,ní ibi tí ó dàbí ẹni pé ilẹ̀ ati ọ̀run ti pàdé, nígbà tí ó ṣe awọsanma lọ́jọ̀,tí ó fi ìpìlẹ̀ orísun omi sọ ilẹ̀, nígbà tí ó pààlà sí ibi tí òkun gbọdọ̀ kọjá,kí omi má baà kọjá ààyè rẹ̀.Nígbà tí ó sàmì sí ibi tí ìpìlẹ̀ ayé wà, ó ń kígbe lóhùn rara lẹ́nu ibodè àtiwọ ìlú,ó ń ké ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pẹlu,ó ń wí pé: èmi ni oníṣẹ́ ọnà tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀,Inú mi a máa dùn lojoojumọ,èmi a sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo. Mo láyọ̀ ninu ayé tí àwọn ẹ̀dá alààyè ń gbé, inú mi sì ń dùn sí àwọn ọmọ eniyan. “Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi, ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà mi. Ẹ gbọ́ ìtọ́ni, kí ẹ sì kọ́gbọ́n,ẹ má sì ṣe àìnáání rẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbọ́ tèmi,tí ó ń ṣọ́nà lojoojumọ ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá mi,tí ó dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé mi. Ẹni tí ó rí mi, rí ìyè,ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹni tí kò bá rí mi, ó pa ara rẹ̀ lára,gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi, ikú ni wọ́n fẹ́ràn.” “Ẹ̀yin eniyan ni mò ń pè,gbogbo ọmọ eniyan ni mò ń ké sí. Ẹ̀yin òpè, ẹ kọ́ ọgbọ́n,ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ fetí sí òye. Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ pataki ni mo fẹ́ sọ.Ohun tí ó tọ́ ni n óo sì fi ẹnu mi sọ. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ ni yóo ti ẹnu mi jáde,nítorí mo kórìíra ọ̀rọ̀ burúkú. Òdodo ni gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi, kò sí ìtànjẹ tabi ọ̀rọ̀ àrékérekè ninu wọn. Gbogbo ọ̀rọ̀ náà tọ́ lójú ẹni tí ó mòye,wọn kò sì ní àbùkù lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀. Ọgbọ́n ati Wèrè. Ọgbọ́n ti kọ́lé,ó ti gbé àwọn òpó rẹ̀ mejeeje nàró. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ sì ni làákàyè. Nípasẹ̀ mi ẹ̀mí rẹ yóo gùn.Ọpọlọpọ ọdún ni o óo sì lò lórí ilẹ̀ alààyè. Bí o bá gbọ́n, o óo jèrè ọgbọ́n rẹ,Bí o bá sì jẹ́ pẹ̀gànpẹ̀gàn, ìwọ nìkan ni o óo jèrè rẹ̀. Aláriwo ni obinrin tí kò gbọ́n,oníwọ̀ra ni, kò sì ní ìtìjú. Á máa jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀,á jókòó ní ibi tí ó ga láàrin ìlú. A máa kígbe pe àwọn tí ń kọjá lọ,àwọn tí ń bá tiwọn lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn, pé, “Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ̀kan, kí ó máa bọ̀!”Ó sì wí fún àwọn òmùgọ̀ pé, “Omi tí eniyan bá jí mu a máa dùn,oúnjẹ tí a bá jí jẹ, oyinmọmọ ni.” Àwọn tí wọ́n bá yà sọ́dọ̀ rẹ̀ kò ní mọ̀ pé ikú wà ní ilé rẹ̀,ati pé inú isà òkú ni àwọn tí wọ́n bá wọ ilé rẹ̀ wọ̀. Ó ti pa ẹran rẹ̀,ó ti pọn ọtí waini rẹ̀,ó sì ti tẹ́ tabili rẹ̀ kalẹ̀. Ó ti rán àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀kí wọn lọ máa kígbe lórí àwọn òkè láàrin ìlú pé: “Ẹ yà síbí ẹ̀yin òpè!”Ó sọ fún ẹni tí kò lọ́gbọ́n pé, “Máa bọ̀, wá jẹ lára oúnjẹ mi,kí o sì mu ninu ọtí waini tí mo ti pò. Fi àìmọ̀kan sílẹ̀, kí o sì yè,kí o máa rin ọ̀nà làákàyè.” Ẹni tí ń tọ́ oníyẹ̀yẹ́ eniyan sọ́nà fẹ́ kan àbùkù,ẹni tí ń bá ìkà eniyan wí ń wá ìfarapa fún ara rẹ̀. Má ṣe bá oníyẹ̀yẹ́ eniyan wí,kí ó má baà kórìíra rẹ,bá ọlọ́gbọ́n wí, yóo sì fẹ́ràn rẹ. Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo tún gbọ́n sí i,kọ́ olódodo, yóo sì tún ní ìmọ̀ kún ìmọ̀. ÌWÉ ORIN KINNI. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náàtí kò gba ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú,tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn,tí kò sì bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA,a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odòtí ń so ní àkókò tí ó yẹ,tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀.Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere. Àwọn eniyan burúkú kò rí bẹ́ẹ̀,ṣugbọn wọ́n dàbí fùlùfúlù tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ. Nítorí náà àwọn eniyan burúkú kò ní rí ìdáláre,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní le wà ní àwùjọ àwọn olódodo. Nítorí OLUWA ń dáàbò bo àwọn olódodo,ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé. Adura Olùpọ́njú. Kí ló dé tí o fi jìnnà réré, OLUWA,tí o sì fara pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú? Ó wó aláìṣẹ̀ mọ́lẹ̀, ó tẹ orí wọn ba,ó sì fi agbára bì wọ́n ṣubú. Ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun ti gbàgbé,OLUWA ti gbé ojú kúrò, kò sì ní rí i laelae.” Dìde, OLUWA; Ọlọrun, wá nǹkankan ṣe sí i;má sì gbàgbé àwọn tí a nilára. Kí ló dé tí eniyan burúkú fi ń kẹ́gàn Ọlọrun,tí ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò ní bi mí?” Ṣugbọn ìwọ Ọlọrun rí gbogbo nǹkan,nítòótọ́, o kíyèsí ìṣòro ati ìyà,kí o baà lè fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san;nítorí ìwọ ni àwọn aláìṣẹ̀ gbẹ́kẹ̀lé,ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìníbaba. Ṣẹ́ eniyan burúkú ati aṣebi lápá,tú àṣírí gbogbo ìwà burúkú rẹ̀,má sì jẹ́ kí ọ̀kan ninu wọn farasin. OLUWA ni ọba lae ati laelae.Àwọn orílẹ̀-èdè yóo pòórá lórí ilẹ̀ rẹ. OLUWA, o óo gbọ́ igbe àwọn tí a nilára;o óo mú wọn lọ́kàn le,o óo sì dẹ etí sílẹ̀ sí igbe wọn kí o lè ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn aláìníbabaati àwọn ẹni tí à ń pọ́n lójú,kí ọmọ eniyan, erùpẹ̀ lásánlàsàn, má lè dẹ́rù bani mọ́. Pẹlu ìgbéraga ni eniyan burúkú fi ń dọdẹ àwọn aláìní;jẹ́ kí ó bọ́ sinu tàkúté tí ó fi àrékérekè dẹ. Eniyan burúkú ń fọ́nnu lórí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀,Ó ń bu ọlá fún wọ̀bìà, ó sì ń kẹ́gàn OLUWA. Eniyan burúkú kò wá Ọlọrun, nítorí ìgbéraga ọkàn rẹ̀,kò tilẹ̀ sí ààyè fún Ọlọrun ninu gbogbo ìrònú rẹ̀. Nígbà gbogbo ni nǹkan ń dára fún un.Ìdájọ́ rẹ, Ọlọrun, ga pupọ, ó ju òye rẹ̀ lọ;ó ń yọ ṣùtì ètè sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó ń rò lọ́kàn ara rẹ̀ pé, kò sí ohun tí ó lè bi òun ṣubú,ati pé ní gbogbo ọjọ́ ayé òun, òun kò ní ní ìṣòro. Ẹnu rẹ̀ kún fún èpè, ẹ̀tàn ati ìhàlẹ̀;ìjàngbọ̀n ati ọ̀rọ̀ ibi sì wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀. Ó ń lúgọ káàkiri létí abúlé,níbi tó fara pamọ́ sí ni ó ti ń pa àwọn aláìṣẹ̀;ó ń fojú ṣọ́ àwọn aláìṣẹ̀ tí yóo pa. Ó fara pamọ́ bíi kinniun tí ó wà ní ibùba;ó fara pamọ́ láti ki aláìní mọ́lẹ̀;ó mú aláìní, ó sì fi àwọ̀n fà á lọ. Orin Ìyìn. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA, gbogbo ilẹ̀ ayé. Ẹ fi ayọ̀ sin OLUWA.Ẹ wá siwaju rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀. Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun,òun ló dá wa, òun ló ni wá;àwa ni eniyan rẹ̀,àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀. Ẹ wọ ẹnubodè rẹ̀ tẹ̀yin tọpẹ́,kí ẹ sì wọ inú àgbàlá rẹ̀ tẹ̀yin tìyìn.Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,kí ẹ sì máa yin orúkọ rẹ̀. Nítorí OLUWA ṣeun;ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae,òtítọ́ rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran. Ìlérí Ọba. N óo kọrin ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo,OLUWA, ìwọ ni n óo máa kọrin ìyìn sí. N óo múra láti hu ìwà pípé pẹlu ọgbọ́n;nígbà wo ni o óo wá sọ́dọ̀ mi?N óo máa fi tọkàntọkàn rin ìrìn pípé ninu ilé mi. N kò ní gba nǹkan burúkú láyè níwájú mi.Mo kórìíra ìṣe àwọn tí wọ́n tàpá sí Ọlọrun.N kò sì ní bá wọn lọ́wọ́ sí nǹkankan. Èròkérò yóo jìnnà sí ọkàn mi,n kò sì ní ṣe ohun ibi kankan, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ níbi,n óo pa á run,n kò sì ní gba alágbèéré ati onigbeeraga láàyè. N óo máa fi ojurere wo àwọn olóòótọ́ ní ilẹ̀ náà,kí wọ́n lè máa bá mi gbé;ẹni tí ó bá sì ń hu ìwà pípé ni yóo máa sìn mí. Ẹlẹ́tàn kankan kò ní gbé inú ilé mi;bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kankan kò ní dúró níwájú mi. Ojoojumọ ni n óo máa pa àwọn eniyan burúkú run ní ilẹ̀ náà,n óo lé gbogbo àwọn aṣebi kúrò ninu ìlú OLUWA. Adura Olùpọ́njú. Gbọ́ adura mi, OLUWA;kí o sì jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ. nítorí ìrúnú ati ibinu rẹ;o gbé mi sókè,o sì jù mí nù. Ọjọ́ ayé mi ń lọ bí òjìji àṣáálẹ́,mo sì ń rọ bíi koríko. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ OLUWA gúnwà títí lae,ọlá rẹ sì wà láti ìran dé ìran. Ìwọ óo dìde, o óo sì ṣàánú Sioni,nítorí ó tó àkókò láti fi ojú àánú wò ó.Àkókò tí o dá tó. Nítorí àwọn òkúta rẹ̀ ṣe iyebíye lójú àwọn iranṣẹ rẹ,àánú rẹ̀ sì ṣeni bí ó tilẹ̀ ti wó dà sinu erùpẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA,gbogbo ọba ayé ni yóo sì máa bẹ̀rù ògo rẹ̀. Nítorí OLUWA yóo tún Sioni kọ́,yóo sì fara hàn ninu ògo rẹ̀. Yóo gbọ́ adura àwọn aláìní,kò sì ní kẹ́gàn ẹ̀bẹ̀ wọn. Kí ẹ kọ èyí sílẹ̀ fún ìran tí ń bọ̀,kí àwọn ọmọ tí a kò tíì bí lè máa yin OLUWA, pé OLUWA bojú wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀,láti ọ̀run ni ó ti bojú wo ayé; Má yọwọ́ lọ́ràn mi lọ́jọ́ ìṣòro!Dẹtí sí adura mi;kí o sì tètè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ké pè ọ́. láti gbọ́ ìkérora àwọn ìgbèkùn,ati láti dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sílẹ̀. Kí á lè pòkìkí orúkọ OLUWA ní Sioni,kí á sì máa yìn ín lógo ní Jerusalẹmu, nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá péjọ tàwọn tọba wọn,láti sin OLUWA. Ó ti gba agbára mi ní àìpé ọjọ́,ó ti gé ọjọ́ ayé mi kúrú. Mo ní, “Áà! Ọlọrun mi, má mú mi kúrò láyé láìpé ọjọ́,ìwọ tí ọjọ́ ayé rẹ kò lópin.” Láti ìgbà laelae ni o ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sì ni ọ̀run. Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ yóo wà títí lae;gbogbo wọn yóo gbó bí aṣọ,o óo pààrọ̀ wọn bí aṣọ;wọn yóo sì di ohun ìpatì. Ṣugbọn ìwọ wà bákan náà,ọjọ́ ayé rẹ kò sì lópin. Ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ yóo ní ibùgbé;bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ wọn yóo fẹsẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ. Nítorí ọjọ́ ayé mi ń kọjá lọ bí èéfín,eegun mi gbóná bí iná ààrò. Ìdààmú bá ọkàn mi, mo rọ bíi koríko,tóbẹ́ẹ̀ tí mo gbàgbé láti jẹun. Nítorí igbe ìrora mi,mo rù kan eegun. Mo dàbí igúnnugún inú aṣálẹ̀,àní, bí òwìwí inú ahoro. Mo dùbúlẹ̀ láìlè sùn,mo dàbí ẹyẹ tí ó dá wà lórí òrùlé. Àwọn ọ̀tá ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru,àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi ń fi orúkọ mi ṣépè. Mò ń jẹ eérú bí oúnjẹ,mo sì ń mu omijé mọ́ omi Ìfẹ́ Ọlọrun. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,fi tinútinú yin orúkọ rẹ̀ mímọ́. Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa,bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa. Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tósí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn,bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa. Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọntí ó bá bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa;ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá. Ọjọ́ ayé ọmọ eniyan dàbí ti koríko,eniyan a sì máa gbilẹ̀ bí òdòdó inú igbó; ṣugbọn bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ kọjá lórí rẹ̀,á rẹ̀ dànù,ààyè rẹ̀ kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn títí ayé ni ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀,sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,òdodo rẹ̀ wà lára arọmọdọmọ wọn. Ó wà lára àwọn tí ó ń pa majẹmu rẹ̀ mọ́,tí wọn sì ń ranti láti pa òfin rẹ̀ mọ́. OLUWA ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run,ó sì jọba lórí ohun gbogbo. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀, Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,ẹ̀yin alágbára tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀,tí ẹ sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ yin OLUWA gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀,ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ yin OLUWA, gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,níbi gbogbo ninu ìjọba rẹ̀.Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi. ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn; ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn,tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé. Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn,tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì. OLUWA a máa dáni lárea sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo fún gbogboàwọn tí a ni lára. Ó fi ọ̀nà rẹ̀ han Mose,ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ han àwọn ọmọ Israẹli. Aláàánú ati olóore ni OLUWA,kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀. Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí,bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ̀ kì í pẹ́ títí ayé. Yíyin Ẹlẹ́dàá. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,OLUWA, Ọlọrun mi, ó tóbi pupọ,ọlá ati iyì ni ó wọ̀ bí ẹ̀wù. Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì;omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè. Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu,ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ. Lẹ́bàá orísun wọnyini àwọn ẹyẹ ń gbé,wọ́n sì ń kọrin lórí igi. Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá.Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ,ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan,kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀; ati ọtí waini tí ń mú inú eniyan dùn,ati epo tí ń mú ojú eniyan dán,ati oúnjẹ tí ń fún ara lókun. Àwọn igi OLUWA ń mu omi ní àmutẹ́rùn,àní àwọn igi kedari Lẹbanoni tí ó gbìn. Lórí wọn ni àwọn ẹyẹ ń tẹ́ ìtẹ́wọn sí,àkọ̀ sì ń kọ́ ilé rẹ̀ sórí igi firi. Òkè gíga ni ilé ewúrẹ́ igbó,abẹ́ àpáta sì ni ibùgbé ehoro. O dá òṣùpá láti máa sàmì àkókò,oòrùn sì mọ àkókò wíwọ̀ rẹ̀. Ó fi ìmọ́lẹ̀ bora bí aṣọ,ó ta ojú ọ̀run bí ẹni taṣọ. O mú kí òkùnkùn ṣú, alẹ́ sì lẹ́,gbogbo ẹranko ìgbẹ́ sìń jẹ kiri. Àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ń bú fún ìjẹ,wọ́n ń wo ojú Ọlọrun fún oúnjẹ. Nígbà tí oòrùn bá là, wọn á wọ́ lọ;wọn á lọ dùbúlẹ̀ sinu ihò wọn. Ọmọ eniyan á sì jáde lọ síbi iṣẹ́ rẹ̀,á lọ síbi làálàá rẹ̀ títí di àṣáálẹ́. OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn.Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ. Ẹ wo òkun bí ó ti tóbi tí ó sì fẹ̀,ó kún fún ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá,nǹkan abẹ̀mí kéékèèké ati ńláńlá. Ibẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi ń gbà lọ,ati Lefiatani tí o dá láti máa ṣeré ninu òkun. Ojú rẹ ni gbogbo wọn ń wò,fún ìpèsè oúnjẹ ní àkókò. Nígbà tí o bá fún wọn, wọn á kó o jọ,nígbà tí o bá la ọwọ́,wọn á jẹ ohun dáradára ní àjẹyó. Bí o bá fojú pamọ́,ẹ̀rù á bà wọ́n,bí o bá gba ẹ̀mí wọn, wọn á kú,wọn á sì pada di erùpẹ̀. Ìwọ tí o tẹ́ àjà ibùgbé rẹ sórí omi,tí o fi ìkùukùu ṣe kẹ̀kẹ́ ogun rẹ,tí o sì ń lọ geere lórí afẹ́fẹ́. Nígbà tí o rán ẹ̀mí rẹ jáde,wọ́n di ẹ̀dá alààyè,o sì sọ orí ilẹ̀ di ọ̀tun. Kí ògo OLUWA máa wà títí lae,kí OLUWA máa yọ̀ ninu iṣẹ́ rẹ̀. Ẹni tí ó wo ilẹ̀, tí ilẹ̀ mì tìtì,tí ó fọwọ́ kan òkè, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ èéfín. N óo kọrin ìyìn sí OLUWAníwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè.N óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi,níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀mí mi bá ń bẹ. Kí àṣàrò ọkàn mi kí ó dùn mọ́ ọn ninunítorí mo láyọ̀ ninu OLUWA. Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ parẹ́ lórí ilẹ̀ ayé,kí àwọn eniyan burúkú má sí mọ́.Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi!Yin OLUWA! Ìwọ tí o fi ẹ̀fúùfù ṣe iranṣẹ,tí o sì fi iná ati ahọ́n iná ṣe òjíṣẹ́ rẹ. Ìwọ tí o gbé ayé kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ rẹ̀,tí kò sì le yẹ̀ laelae. O fi ibú omi bò ó bí aṣọ,omi sì borí àwọn òkè ńlá. Nígbà tí o bá wọn wí, wọ́n sá,nígbà tí o sán ààrá, wọ́n sá sẹ́yìn. Wọ́n ṣàn kọjá lórí òkèlọ sí inú àfonífojì,sí ibi tí o yàn fún wọn. O ti pa ààlà tí wọn kò gbọdọ̀ kọjá,kí wọn má baà tún bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́. Ọlọrun ati Àwọn Eniyan Rẹ̀. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀,ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí òfin,àní fún Israẹli gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé, ó ní: “Ẹ̀yin ni n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún,yóo jẹ́ ìpín yín tí ẹ óo jogún.” Nígbà tí wọ́n kéré ní iye,tí wọn kò tíì pọ̀ rárá, tí wọn sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà, tí wọn ń káàkiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,láti ìjọba kan dé òmíràn, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn. Ó ní, “Ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹni àmìòróró mi,ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe àwọn wolii mi níbi.” Nígbà kan, ó mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà:ó ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ mọ́ wọn lẹ́nu. Ṣugbọn ó kọ́ rán ọkunrin kan ṣáájú wọn,Josẹfu, ẹni tí a tà lẹ́rú. Wọ́n so ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀,wọ́n ti ọrùn rẹ̀ bọ irin, títí ìgbà tí ohun tí ó sọ fi ṣẹ,tí OLUWA sì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin ìyìn sí i,ẹ sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ribiribi rẹ̀. Ọba ranṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀,aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè sì dá a sílẹ̀. Ó fi jẹ aláṣẹ ilé rẹ̀,ati alákòóso gbogbo nǹkan ìní rẹ̀; láti máa ṣe olórí àwọn ìjòyè rẹ̀,kí ó sì máa kọ́ àwọn àgbà ìlú ní ìmọ̀. Lẹ́yìn náà, Israẹli dé sí Ijipti,Jakọbu ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Hamu. OLUWA mú kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ sí i,ó sì mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ. Ó yí àwọn ará Ijipti lọ́kàn pada,tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kórìíra àwọn eniyan rẹ̀,tí wọ́n sì hùwà àrékérekè sí àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ó rán Mose, iranṣẹ rẹ̀,ati Aaroni, ẹni tí ó yàn. Wọ́n ṣe iṣẹ́ àmì rẹ̀ ní ilẹ̀ náà,wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hamu, Ọlọrun rán òkùnkùn, ilẹ̀ sì ṣú,ṣugbọn wọ́n ṣe oríkunkun sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,ó sì mú kí ẹja wọn kú. Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn,kí ọkàn àwọn tí ń wá OLUWA ó máa yọ̀. Ọ̀pọ̀lọ́ ń tú jáde ní ilẹ̀ wọn,títí kan ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn. Ọlọrun sọ̀rọ̀, eṣinṣin sì rọ́ dé,iná aṣọ sì bo gbogbo ilẹ̀ wọn. Ó rọ̀jò yìnyín lé wọn lórí,mànàmáná sì ń kọ káàkiri ilẹ̀ wọn. Ó kọlu àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn,ó sì wó àwọn igi ilẹ̀ wọn. Ó sọ̀rọ̀, àwọn eṣú sì rọ́ dé,ati àwọn tata tí kò lóǹkà; wọ́n jẹ gbogbo ewé tí ó wà ní ilẹ̀ wọn,ati gbogbo èso ilẹ̀ náà. Ó kọlu gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ wọn,àní, gbogbo àrẹ̀mọ ilẹ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde,tàwọn ti fadaka ati wúrà,kò sì sí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yà kankan tí ó ṣe àìlera. Inú àwọn ará Ijipti dùn nígbà tí wọ́n jáde,nítorí ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli ń bà wọ́n. OLUWA ta ìkùukùu bò wọ́n,ó sì pèsè iná láti tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lóru. Ẹ wá ojurere OLUWA ati agbára rẹ̀,ẹ máa wá ojurere rẹ̀ nígbà gbogbo. Wọ́n bèèrè ẹran, ó fún wọn ní àparò,ó sì pèsè oúnjẹ àjẹtẹ́rùn fún wọn láti ọ̀run. Ó la àpáta, omi tú jáde,ó sì ṣàn ninu aṣálẹ̀ bí odò. Nítorí pé ó ranti ìlérí mímọ́ rẹ̀,ati Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀. Ó fi ayọ̀ kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde,ó kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jáde pẹlu orin. Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,wọ́n sì jogún èrè iṣẹ́ àwọn eniyan náà. Kí wọ́n lè máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ,kí wọ́n sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́.Ẹ yin OLUWA! Ẹ ranti iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe,ẹ ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ati ìdájọ́ rẹ̀. Ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀,ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀. OLUWA ni Ọlọrun wa,ìdájọ́ rẹ̀ kárí gbogbo ayé. Títí lae ni ó ń ranti majẹmu rẹ̀,ó ranti àṣẹ tí ó pa fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran, majẹmu tí ó bá Abrahamu dá,ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Isaaki, Oore OLUWA fún Àwọn Eniyan Rẹ̀. Ẹ yin OLUWA!Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeunnítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn,ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Omi bo àwọn ọ̀tá wọn,ẹyọ ẹnìkan kò sì là. Nígbà náà ni wọ́n tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́,wọ́n sì kọrin yìn ín. Kò pẹ́ tí wọ́n tún fi gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,wọn kò sì dúró gba ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọ́n ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ní aṣálẹ̀,wọ́n sì dán Ọlọrun wò. Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè,ṣugbọn ó fi àìsàn ajẹnirun ṣe wọ́n. Nígbà tí wọ́n ṣe ìlara sí Mose ninu ibùdó,ati sí Aaroni, ẹni mímọ́ OLÚWA. Ilẹ̀ yanu, ó gbé Datani mì,ó sì bo Abiramu ati àwọn tí ó tẹ̀lé e mọ́lẹ̀. Iná sọ láàrin wọn,ó sì jó àwọn eniyan burúkú náà run. Wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ní Horebu,wọ́n sì bọ ère tí wọ́n dà. Ta ló lè sọ iṣẹ́ agbára OLUWA tán?Ta ló sì lè fi gbogbo ìyìn rẹ̀ hàn? Wọ́n gbé ògo Ọlọrunfún ère mààlúù tí ń jẹ koríko. Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn,tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti, ó ṣe, iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu,ati ohun ẹ̀rù lẹ́bàá òkun pupa. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run,bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀,tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀,láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run. Wọn kò bìkítà fún ilẹ̀ dáradára náà,wọn kò sì ní igbagbọ ninu ọ̀rọ̀ OLUWA. Wọ́n ń kùn ninu àgọ́ wọn,wọn kò sì fetí sí ohùn OLUWA. Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ sókè, ó búra fún wọnpé òun yóo jẹ́ kí wọ́n kú sí aṣálẹ̀, ati pé òun yóo fọ́n àwọn ìran wọn káàkiriàwọn orílẹ̀-èdè. Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali ti Peori,wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú. Wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú OLUWA bínú,àjàkálẹ̀ àrùn sì bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́,àwọn tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà nígbà gbogbo. Nígbà náà ni Finehasi dìde, ó bẹ̀bẹ̀ fún wọn,àjàkálẹ̀ àrùn sì dáwọ́ dúró. A sì kà á kún òdodo fún un,láti ìrandíran títí lae. Wọ́n mú OLUWA bínú lẹ́bàá omi Meriba,wọ́n sì fi tiwọn kó bá Mose, nítorí wọ́n mú Mose bínú,ọ̀rọ̀ tí kò yẹ sì ti ẹnu rẹ̀ jáde. Wọn kò pa àwọn eniyan ilẹ̀ náà run,gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn, ṣugbọn wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè náà,wọ́n sì kọ́ ìṣe wọn. Wọ́n bọ àwọn oriṣa wọn,èyí sì fa ìpalára fún wọn. Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn bọ oriṣa. Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,àní, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkunrin,ati ti àwọn ọmọbinrin wọn,tí wọ́n fi bọ àwọn oriṣa ilẹ̀ Kenaani;wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di aláìmọ́. Nítorí náà, wọ́n fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,wọ́n sì sọ ara wọn di alágbèrè. Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ńṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ.Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là. Nígbà náà ni inú bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀,ó sì kórìíra àwọn ẹni ìní rẹ̀. Ó fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́,títí tí àwọn tí ó kórìíra wọn fi jọba lé wọn lórí. Àwọn ọ̀tá wọn ni wọ́n lára,wọ́n sì fi agbára mú wọn sìn. Ọpọlọpọ ìgbà ni ó gbà wọ́n sílẹ̀,ṣugbọn wọ́n ti pinnu láti máa tàpá sí i,OLUWA sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Sibẹsibẹ, ninu ìnira wọn, ó ṣàánú wọn,nígbà tí ó gbọ́ igbe wọn. Nítorí tiwọn, ó ranti majẹmu tí ó dá,ó sì yí ìpinnu rẹ̀ pada nítorí ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ó jẹ́ kí àánú wọn ṣe gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn. Gbà wá, OLUWA, Ọlọrun wa,kí o sì kó wa kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,kí á lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,kí á sì lè máa ṣògo ninu ìyìn rẹ. Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli,lae ati laelae.Kí gbogbo eniyan máa wí pé, “Amin!” Ẹ yin OLUWA! Kí n lè rí ire àwọn àyànfẹ́ rẹkí n lè ní ìpín ninu ayọ̀ àwọn eniyan rẹ,kí n sì lè máa ṣògo pẹlu àwọn tí ó jẹ́ eniyan ìní rẹ. A ti ṣẹ̀, àtàwa, àtàwọn baba wa,a ti ṣe àìdára, a sì ti hùwà burúkú. Nígbà tí àwọn baba ńlá wa wà ní Ijipti,wọn kò náání iṣẹ́ ìyanu rẹ,wọn kò sì ranti bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti pọ̀ tó.Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo lẹ́bàá òkun pupa. Sibẹsibẹ, ó gbà wọ́n là, nítorí orúkọ rẹ̀;kí ó lè fi títóbi agbára rẹ̀ hàn. Ó bá òkun pupa wí, òkun pupa gbẹ,ó sì mú wọn la ibú já bí ẹni rìn ninu aṣálẹ̀. Yíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Àwọn kan jókòó ninu òkùnkùn pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,wọ́n wà ninu ìgbèkùn ati ìpọ́njú, a sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n, nítorí pé wọ́n tàpá sí òfin Ọlọrun,wọ́n sì pẹ̀gàn ìmọ̀ràn ọ̀gá ògo. Làálàá mú kí agara dá ọkàn wọn,wọ́n ṣubú lulẹ̀ láìsí olùrànlọ́wọ́. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì gbà wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó yọ wọ́n kúrò ninu òkùnkùn ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,ó sì já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Nítorí pé ó fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ,ó sì gé ọ̀pá ìdábùú irin ní àgéjá. Àwọn kan ninu wọn di òmùgọ̀nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,ojú sì pọ́n wọn nítorí àìdára wọn. Oúnjẹ rùn sí wọn,wọ́n sì súnmọ́ bèbè ikú. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Kí àwọn tí OLUWA ti rà pada kí ó wí bẹ́ẹ̀,àní, àwọn tí ó yọ kúrò ninu ìpọ́njú, Ó sọ̀rọ̀, ó sì mú wọn lára dá,ó tún kó wọn yọ ninu ìparun. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní, nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Kí wọn máa rú ẹbọ ọpẹ́,kí wọn sì máa fi orin ayọ̀ ròyìn iṣẹ́ rẹ̀. Àwọn kan wọ ọkọ̀ ojú omi,wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun, wọ́n rí ìṣe OLUWA,àní iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ninu ibú. Ó pàṣẹ, ìjì líle sì bẹ̀rẹ̀ sí jà,tóbẹ́ẹ̀ tí ìgbì omi fi ru sókè. Àwọn ọkọ̀ ojú omi fò sókè roro,wọ́n sì tún já wá sílẹ̀ dòò, sinu ibú,jìnnìjìnnì bò wọ́n ninu ewu tí wọ́n wà. Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n káàkiri bí ọ̀mùtí,gbogbo ọgbọ́n sì parẹ́ mọ́ wọn ninu. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró,ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀. tí ó kó wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀n-ọn-nì,láti ìhà ìlà oòrùn ati láti ìhà ìwọ̀ oòrùn,láti ìhà àríwá ati láti ìhà gúsù. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nígbà tí ilẹ̀ rọ̀,ó sì mú kí wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté ìfẹ́ wọn. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Kí wọn gbé e ga láàrin ìjọ eniyan,kí wọn sì yìn ín ní àwùjọ àwọn àgbà. Ó sọ odò di aṣálẹ̀,ó sọ orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ, ó sọ ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀ oníyọ̀,nítorí ìwà burúkú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Ó sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,ó sì sọ ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi. Ó jẹ́ kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé ibẹ̀,wọ́n sì tẹ ìlú dó, láti máa gbé. Wọ́n dáko, wọ́n gbin àjàrà,wọ́n sì kórè lọpọlọpọ. Ó bukun wọn, ó mú kí wọn bí sí i lọpọlọpọ,kò sì jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọ́n dínkù. Nígbà tí wọ́n dínkù, tí a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,nípa ìnira, ìpọ́njú, ati ìṣòro, Àwọn kan ń káàkiri ninu aṣálẹ̀,wọn kò sì rí ọ̀nà dé ìlú tí wọ́n lè máa gbé. ó da ẹ̀gàn lu àwọn ìjòyè,ó sì mú kí wọn máa rìn kiri ní aṣálẹ̀,níbi tí kò sí ọ̀nà. Ṣugbọn ó yọ aláìní kúrò ninu ìpọ́njú,ó sì mú kí ìdílé wọn pọ̀ sí i bí agbo ẹran. Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn,a sì pa àwọn eniyan burúkú lẹ́nu mọ́. Kí ẹni tí ó gbọ́n kíyèsí nǹkan wọnyi;kí ó sì fi òye gbé ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀. Ebi pa wọ́n, òùngbẹ gbẹ wọ́n,ó sì rẹ̀ wọ́n wá láti inú. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì yọ wọ́n kúrò ninu ìṣẹ́ wọn. Ó kó wọn gba ọ̀nà tààrà jáde,lọ sí ìlú tí wọ́n lè máa gbé. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún àwọn ọmọ eniyan. Nítorí pé ó fi omi tẹ́ àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ lọ́rùn,ó sì fi oúnjẹ dáradára bọ́ àwọn tí ebi ń pa ní àbọ́yó. Adura Ìrànlọ́wọ́ láti Borí Ọ̀tá. Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrunọkàn mi dúró ṣinṣin.N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́.Jí, ìwọ ọkàn mi! Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà?Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu? Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀?Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa lọ sójú ogun mọ́. Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa,nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan. Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọ́run, a óo ṣe akin;nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀. Ẹ jí ẹ̀yin ohun èlò ìkọrin ati hapu!Èmi fúnra mi náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, OLUWA, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwọn eniyan,n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ,òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Kí á gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, Ọlọrun,kí ògo rẹ sì kárí gbogbo ayé. Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là,fi ọwọ́ agbára rẹ gbà wá, kí o sì dá mi lóhùn. Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀,ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu,n óo sì pín àfonífojì Sukotu. Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase.Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi,Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi. Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé,n óo sì hó ìhó ìṣẹ́gun lórí Filistia.” Ìráhùn Ẹni tí Ó Wà ninu Ìṣòro. Má dákẹ́, ìwọ Ọlọrun tí mò ń yìn. Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di alárìnká,kí wọn máa ṣagbe kiri;kí á lé wọn jáde kúrò ninu ahoro tí wọn ń gbé. Kí ẹni tí ó jẹ lówó gba gbogbo ohun ìní rẹ̀,kí ẹni ẹlẹ́ni sì kó èrè iṣẹ́ rẹ̀. Kí ó má bá aláàánú pàdé,kí ẹnikẹ́ni má sì ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ti di aláìníbaba. Kí ìran rẹ̀ run,kí orúkọ rẹ̀ parẹ́ lórí àwọn ọmọ rẹ̀. Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀,kí ó má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ ìyá rẹ̀ rẹ́. Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn nígbà gbogbo,kí á má sì ranti ìran wọn mọ́ láyé. Nítorí pé kò ronú láti ṣàánú,ṣugbọn ó ṣe inúnibíni talaka ati aláìní,ati sí oníròbìnújẹ́ títí a fi pa wọ́n. Ó fẹ́ràn láti máa ṣépè;nítorí náà kí èpè rẹ̀ dà lé e lórí;inú rẹ̀ kò dùn sí ìre,nítorí náà kí ìre jìnnà sí i. Ó gbé èpè wọ̀ bí ẹ̀wù,kí èpè mù ún bí omi,kí ó sì wọ inú egungun rẹ̀ dé mùdùnmúdùn. Kí èpè di aṣọ ìbora fún un,ati ọ̀já ìgbànú. Nítorí pé ẹnu àwọn eniyan burúkú ati tiàwọn ẹlẹ́tàn kò dákẹ́,wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké nípa mi. Bẹ́ẹ̀ ni kí OLUWA ṣe sí àwọn ọ̀tá mi,àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi nípa mi! Ṣugbọn, ìwọ OLUWA Ọlọrun mi, gbèjà minítorí orúkọ rẹ, gbà mí!Nítorí ìfẹ́ rere rẹ tí kì í yẹ̀. Nítorí pé talaka ati aláìní ni mí,ọkàn mí bàjẹ́ lọpọlọpọ. Mò ń parẹ́ lọ bí òjìji àṣáálẹ́,a ti gbọ̀n mí dànù bí eṣú. Ẹsẹ̀ mi kò ranlẹ̀ mọ́ nítorí ààwẹ̀ gbígbà,mo rù kan egungun. Mo di ẹni ẹ̀gàn níwájú àwọn ọ̀tá mi,wọ́n ń wò mí ní àwòmirí. Ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, Ọlọrun mi,gbà mí, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni èyí,kí wọn mọ̀ pé, ìwọ OLUWA ni o ṣe é. Kí wọn máa ṣépè, ṣugbọn kí ìwọ máa súre.Kí ojú ti àwọn alátakò mi,kí inú èmi, iranṣẹ rẹ, sì máa dùn. Kí ìtìjú bo àwọn ọ̀tá mi bi aṣọ,àní, kí wọn gbé ìtìjú wọ̀ bí ẹ̀wù. Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ káàkiri nípa mi,wọ́n sì ń gbógun tì mí láìnídìí. N óo máa fi ẹnu mi yin OLUWA gidigidi,àní, n óo máa yìn ín ní àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan. Nítorí pé ó dúró ti aláìníláti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ó dájọ́ ikú fún un. Èmi fẹ́ràn wọn; ṣugbọn ẹ̀sùn ni wọ́n fi ń kàn mí,sibẹ, adura ni mò ń gbà fún wọn. Ibi ni wọ́n fí ń san oore fún mi,ìkórìíra ni wọ́n sì fi ń san ìfẹ́ tí mo ní sí wọn. Yan eniyan burúkú tì í,jẹ́ kí ẹlẹ́sùn èké kó o sẹ́jọ́. Nígbà tí a bá ń dá ẹjọ́ rẹ̀,jẹ́ kí wọn dá a lẹ́bi;kí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ di ọ̀ràn sí i lọ́rùn. Ṣe é ní ẹlẹ́mìí kúkúrú,kí ohun ìní rẹ̀ di ti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà. Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìníbaba,kí aya rẹ̀ di opó. OLUWA ni Igbẹkẹle Àwọn Olódodo. OLUWA ni mo sá di;ẹ ṣe lè wí fún mi pé,“Fò lọ sórí òkè bí ẹyẹ; ẹ wo àwọn eniyan burúkú bí wọ́n ti kẹ́ ọfà;wọ́n fa ọrun;wọ́n sì fi òkùnkùn bojú láti ta olódodo lọ́fà. Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́,kí ni olódodo lè ṣe?” OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀,ìtẹ́ rẹ̀ wà lọ́run;OLUWA ń kíyèsí àwọn ọmọ eniyan,ó sì ń yẹ̀ wọ́n wò. OLUWA ń yẹ àwọn olódodo, ati eniyan burúkú wò,ṣugbọn tọkàntọkàn ni ó kórìíra àwọn tí ó fẹ́ràn ìwà ipá. Yóo rọ̀jò ẹ̀yinná ati imí ọjọ́ gbígbóná sórí àwọn eniyan burúkú;ìjì gbígbóná ni yóo sì jẹ́ ìpín wọn. Nítorí olódodo ni OLUWA, ó sì fẹ́ràn òdodo;àwọn olóòótọ́ ni yóo rí ojú rẹ̀. OLUWA ati Àyànfẹ́ Ọba Rẹ̀. OLUWA wí fún oluwa mi, ọba, pé,“Jókòó sí apá ọ̀tún mi,títí tí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹdi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” OLUWA yóo na ọ̀pá àṣẹ rẹ tí ó lágbára láti Sioni.O óo jọba láàrin àwọn ọ̀tá rẹ. Àwọn eniyan rẹ yóo fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀,lọ́jọ́ tí o bá ń kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ lórí òkè mímọ́.Àwọn ọ̀dọ́ yóo jáde tọ̀ ọ́ wá bí ìrì òwúrọ̀. OLUWA ti búra, kò sì ní yí ọkàn rẹ̀ pada, pé,“Alufaa ni ọ́ títí lae,nípasẹ̀ Mẹlikisẹdẹki.” OLUWA wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,yóo rún àwọn ọba wómúwómú ní ọjọ́ ibinu rẹ̀. Yóo ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,ọpọlọpọ òkú ni yóo sì sùn ninu wọn;yóo sì run àwọn ìjòyè káàkiri ilẹ̀ ayé. Ọba yóo mu omi ninu odò ẹ̀bá ọ̀nà,nítorí náà yóo sì gbé orí rẹ̀ sókè bí aṣẹ́gun. Yin OLUWA. Ẹ yin OLUWA!N óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tọkàntọkàn,láàrin àwọn olódodo,ati ní àwùjọ àwọn eniyan. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,gbogbo àwọn tí ó bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, á máa ní ìmọ̀ pípé.Títí lae ni ìyìn rẹ̀. Iṣẹ́ OLUWA tóbi,àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí i sì ń wá a kiri. Iṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá, ó sì lógo,òdodo rẹ̀ sì wà títí lae. OLUWA mú kí á máa ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀,olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, àánú rẹ̀ sì pọ̀. A máa pèsè oúnjẹ fún àwọn tí wọn bẹ̀rù rẹ̀,a sì máa ranti majẹmu rẹ̀ títí lae. Ó ti fi agbára iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn eniyan rẹ̀,nípa fífún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tọ́, ó sì tọ̀nà,gbogbo ìlànà rẹ̀ sì dájú. Wọ́n wà títí lae ati laelae,ní òtítọ́ ati ìdúróṣinṣin. Ó ṣètò ìràpadà fún àwọn eniyan rẹ̀,ó fi ìdí majẹmu rẹ̀ múlẹ̀ títí lae,mímọ́ ni orúkọ rẹ̀, ó sì lọ́wọ̀. Ayọ̀ Ẹni Rere. Ẹ yin OLUWA!Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA,tí inú rẹ̀ sì dùn lọpọlọpọ sí òfin rẹ̀. Ìbànújẹ́ yóo bá eniyan burúkú nígbà tí ó bá rí i.Yóo pa eyín keke, yóo pòórá,ìfẹ́ rẹ̀ yóo sì di asán. Àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ yóo jẹ́ alágbára láyé,a óo sì bukun ìran ẹni tí ó dúró ṣinṣin. Ọlá ati ọlà yóo wà ní ilé rẹ̀,Òdodo rẹ̀ wà títí lae. Ìmọ́lẹ̀ yóo tàn fún olódodo ninu òkùnkùn,olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, aláàánú ni, a sì máa ṣòdodo. Yóo máa dára fún ẹni tí ó bá lójú àánú, tí ó sì ń yáni ní nǹkan,tí ó ń ṣe ẹ̀tọ́ ní gbogbo ọ̀nà. A kò ní ṣí olódodo ní ipò pada lae,títí ayé ni a óo sì máa ranti rẹ̀. Ìròyìn ibi kì í bà á lẹ́rù,ọkàn rẹ̀ dúró ṣinṣin, ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ọkàn rẹ̀ a máa balẹ̀, ẹ̀rù kì í bà á,níkẹyìn, èrò rẹ̀ a sì máa ṣẹ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó lawọ́, á máa ṣoore fún àwọn talaka,òdodo rẹ̀ wà títí lae,yóo di alágbára, a óo sì dá a lọ́lá. Yíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀. Ẹ yin OLUWA!Ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ OLUWA.Ẹ yin orúkọ OLUWA. Kí á yin orúkọ OLUWA,láti ìsinsìnyìí lọ títí laelae. Láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn,kí á máa yin orúkọ OLUWA. OLUWA ju gbogbo orílẹ̀-èdè lọ,ògo rẹ̀ sì ga ju ọ̀run lọ. Ta ló dàbí OLUWA Ọlọrun wa,tí ó gúnwà sí òkè ọ̀run, ẹni tí ó bojú wo ilẹ̀láti wo ọ̀run ati ayé? Ó gbé talaka dìde láti inú erùpẹ̀,ó sì gbé aláìní sókè láti orí eérú, láti mú wọn jókòó láàrin àwọn ìjòyè,àní, àwọn ìjòyè àwọn eniyan rẹ̀. Ó sọ àgàn di ọlọ́mọ,ó sọ ọ́ di abiyamọ onínúdídùn.Ẹ máa yin OLUWA. Orin Ìrékọjá. Nígbà tí Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti,tí àwọn ọmọ Jakọbu jáde kúrò láàrin àwọn tí ń sọ èdè àjèjì, Juda di ilé mímọ́ rẹ̀,Israẹli sì di ìjọba rẹ̀. Òkun rí i, ó sá,Jọdani rí i, ó pada sẹ́yìn. Àwọn òkè ńláńlá ń fò bí àgbò,àwọn òkè kéékèèké ń fò bí ọmọ aguntan. Kí ló dé, tí o fi sá, ìwọ òkun?Kí ló ṣẹlẹ̀ tí o fi pada sẹ́yìn, ìwọ Jọdani? Ẹ̀yin òkè ńlá, kí ló dé tí ẹ fi fò bí àgbò?Ẹ̀yin òkè kéékèèké, kí ló ṣẹlẹ̀ tí ẹ fi fò bí ọmọ aguntan? Wárìrì níwájú OLUWA, ìwọ ilẹ̀,wárìrì níwájú Ọlọrun Jakọbu. Ẹni tí ó sọ àpáta di adágún omi,tí ó sì sọ akọ òkúta di orísun omi. Ọlọrun Òdodo. Ògo kì í ṣe fún wa, OLUWA, Kì í ṣe fún wa,orúkọ rẹ nìkan ṣoṣo ni kí á yìn lógo,nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati nítorí òtítọ́ rẹ. Ẹ̀yin ìdílé Aaroni, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín. Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ gbẹ́kẹ̀lé e,òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín. OLUWA ranti wa, yóo bukun wa,yóo bukun ilé Israẹli,yóo bukun ìdílé Aaroni. Yóo bukun àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,ati àwọn ọlọ́lá ati àwọn mẹ̀kúnnù. OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ máa bí sí i,àtẹ̀yin àtàwọn ọmọ yín. Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun yín! OLUWA ló ni ọ̀run,ṣugbọn ó fi ayé fún àwọn eniyan. Àwọn òkú kò lè yin OLUWA,àní àwọn tí wọ́n ti dákẹ́ ninu ibojì. Ṣugbọn àwa yóo máa yin OLUWA,láti ìsinsìnyìí lọ, ati títí laelae.Ẹ máa yin OLUWA. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi bèèrè pé,níbo ni Ọlọrun wa wà? Ọlọrun wa wà ní ọ̀run,ó ń ṣe ohun tí ó wù ú. Fadaka ati wúrà ni ère tiwọn,iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n. Wọ́n ní ẹnu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀,wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò ríran. Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn,wọ́n nímú, ṣugbọn wọn kò gbóòórùn. Wọ́n lọ́wọ́, ṣugbọn wọn kò lè lò ó,wọ́n lẹ́sẹ̀, ṣugbọn wọn kò lè rìn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbin. Àwọn tí ó ń yá àwọn ère náà dàbí wọn,bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé wọn. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín. Orin Ọpẹ́. Mo fẹ́ràn OLUWA nítorí pé ó gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ mi. Igbagbọ mi kò yẹ̀, nígbà tí mo tilẹ̀ wí pé,“Ìpọ́njú dé bá mi gidigidi.” Mo wí ninu ìdààmú ọkàn pé,“Èké ni gbogbo eniyan.” Kí ni n óo san fún OLUWA,nítorí gbogbo oore rẹ̀ lórí mi? N óo mu ẹbọ nǹkan mímu wá fún OLUWA,n óo sì pe orúkọ rẹ̀. N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWA,lójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. Iyebíye ni ikú àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lójú OLUWA. OLUWA, iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́,iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́, àní, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ.O ti tú ìdè mi. N óo rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ,n óo sì pe orúkọ rẹ OLUWA. N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWAlójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, ninu àgbàlá ilé OLUWA,láàrin rẹ, ìwọ ìlú Jerusalẹmu.Ẹ máa yin OLUWA! Nítorí pé ó tẹ́tí sí mi,nítorí náà, n óo máa ké pè éníwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè. Tàkúté ikú yí mi ká;ìrora isà òkú dé bá mi;ìyọnu ati ìnira sì bò mí mọ́lẹ̀. Nígbà náà ni mo ké pe OLUWA,mo ní, “OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gbà mí!” Olóore ọ̀fẹ́ ati olódodo ni OLUWA,aláàánú ni Ọlọrun wa. OLUWA a máa pa àwọn onírẹ̀lẹ̀ mọ́;nígbà tí a rẹ̀ mí sílẹ̀, ó gbà mí. Sinmi ìwọ ọkàn mi, bíi ti àtẹ̀yìnwá,nítorí pé OLUWA ṣeun fún ọ lọpọlọpọ. Nítorí ìwọ OLUWA ti gba ọkàn mi lọ́wọ́ ikú,o gba ojú mi lọ́wọ́ omijé,o sì gba ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú. Mò ń rìn níwájú OLUWA, lórí ilẹ̀ alààyè. Yíyin OLUWA. Ẹ máa yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè!Ẹ yìn ín gbogbo ẹ̀yin eniyan, Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tóbi sí wa,òtítọ́ rẹ̀ sì wà títí laelae.Ẹ máa yin OLUWA. Adura Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Gbogbo orílẹ̀-èdè dòòyì ká mi,ṣugbọn ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run! Wọ́n yí mi ká, àní, wọ́n dòòyì ká mi,ṣugbọn ni orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run! Wọ́n ṣùrù bò mí bí oyin,ṣugbọn kíá ni wọ́n kú bí iná ìṣẹ́pẹ́;ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run. Wọ́n gbógun tì mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ ṣubú,ṣugbọn OLUWA ràn mí lọ́wọ́. OLUWA ni agbára ati orin mi,ó ti di olùgbàlà mi. Ẹ gbọ́ orin ayọ̀ ìṣẹ́gun,ninu àgọ́ àwọn olódodo.“Ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá. A gbé ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ga,ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá!” N ò ní kú, yíyè ni n óo yè,n óo sì máa fọnrere nǹkan tí OLUWA ṣe. OLUWA jẹ mí níyà pupọ,ṣugbọn kò fi mí lé ikú lọ́wọ́. Ṣí ìlẹ̀kùn òdodo fún mi,kí n lè gba ibẹ̀ wọlé,kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA. Jẹ́ kí Israẹli wí pé,“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.” Èyí ni ẹnu ọ̀nà OLUWA;àwọn olódodo yóo gba ibẹ̀ wọlé. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí pé o gbọ́ ohùn mi,o sì ti di olùgbàlà mi. Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,ni ó di pataki igun ilé. OLUWA ló ṣe èyí;ó sì jẹ́ ohun ìyanu lójú wa. Òní ni ọjọ́ tí OLUWA dá,ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn. OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, gbà wá,OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí á ṣe àṣeyege. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ OLUWA,láti inú ilé rẹ ni a ti ń yìn ọ́, OLUWA. OLUWA ni Ọlọrun, ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí wa.Pẹlu ẹ̀ka igi lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìwọ́de ẹbọ náà,títí dé ibi ìwo pẹpẹ. Ìwọ ni Ọlọrun mi,n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ.Ìwọ ni Ọlọrun mi,n óo máa gbé ọ ga. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Kí àwọn ará ilé Aaroni wí pé,“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.” Kí àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA wí pé,“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.” Ninu ìpọ́njú, mo ké pe OLUWA,ó dá mi lóhùn, ó sì tú mi sílẹ̀. Nígbà tí OLUWA wà pẹlu mi, ẹ̀rù kò bà mí.Kí ni eniyan lè fi mí ṣe? OLUWA wà pẹlu mi láti ràn mí lọ́wọ́,nítorí náà, n óo wo àwọn tí wọ́n kórìíra mipẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun. Ó sàn láti sá di OLUWA,ju ati gbẹ́kẹ̀lé eniyan lọ. Ó sàn láti sá di OLUWA,ju ati gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè. Òfin OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ìgbé ayé wọn kò lábàwọ́n,àní àwọn tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ,má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ. Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ,nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ. N kò rin ọ̀nà ibi kankan,kí n lè pa òfin rẹ mọ́. N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ,nítorí pé o ti kọ́ mi. Ọ̀rọ̀ rẹ dùn mọ́ mi pupọ,ó dùn ju oyin lọ. Nípa ẹ̀kọ́ rẹ ni mo fi ní òye,nítorí náà mo kórìíra gbogbo ìwà èké. Ọ̀rọ̀ rẹ ni àtùpà fún ẹsẹ̀ mi,òun ni ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà mi. Mo ti búra, n óo sì mú un ṣẹ,pé n óo máa pa òfin òdodo rẹ mọ́. Ojú ń pọ́n mi lọpọlọpọ,sọ mí di alààyè, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Gba ẹbọ ìyìn àtọkànwá mi, OLUWA,kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Ayé mi wà ninu ewu nígbà gbogbo,ṣugbọn n kò gbàgbé òfin rẹ. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn,kí n má baà ṣẹ̀ ọ́. Àwọn eniyan burúkú ti dẹ okùn sílẹ̀ dè mí,ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀. Ìlànà rẹ ni ogún mi títí lae,nítorí pé òun ni ayọ̀ mi. Mo ti pinnu láti máa tẹ̀lé ìlànà rẹ nígbà gbogbo,àní, títí dé òpin. Mo kórìíra àwọn oníyèméjì,ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ. Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi ati asà mi,mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi,kí n lè pa òfin Ọlọrun mi mọ́. Gbé mi ró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, kí n lè wà láàyè,má sì dójú ìrètí mi tì mí. Gbé mi ró, kí n lè wà láìléwu,kí n lè máa ka ìlànà rẹ sí nígbà gbogbo. O ti kọ gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò ninu ìlànà rẹ sílẹ̀,nítorí pé asán ni gbogbo ẹ̀tàn wọn. O ti pa àwọn eniyan burúkú tì, bí ìdàrọ́ irin,nítorí náà ni mo ṣe fẹ́ràn ìlànà rẹ. Ìyìn ni fún ọ, OLUWA,kọ́ mi ní ìlànà rẹ! Mo wárìrì nítorí pé mo bẹ̀rù rẹ,mo sì bẹ̀rù ìdájọ́ rẹ. Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ,má fi mí sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń ni mí lára. Ṣe ìlérí ìrànlọ́wọ́ fún ire èmi iranṣẹ rẹ,má sì jẹ́ kí àwọn onigbeeraga ni mí lára. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,níbi tí mo tí ń retí ìgbàlà rẹ,ati ìmúṣẹ ìlérí òdodo rẹ. Ṣe sí èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Iranṣẹ rẹ ni mí,fún mi lóye, kí n lè mọ ìlànà rẹ. OLUWA, ó tó àkókò fún ọ láti ṣe nǹkankan,nítorí àwọn eniyan ń rú òfin rẹ. Nítorí náà ni èmi ṣe fẹ́ràn òfin rẹju wúrà lọ; àní, ju ojúlówó wúrà. Nítorí náà, èmi ń tẹ̀lé gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ,mo sì kórìíra gbogbo ọ̀nà èké. Òfin rẹ dára,nítorí náà ni mo ṣe ń pa wọ́n mọ́. Mo fi ẹnu mi kéde gbogbo àṣẹ tí o pa. Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ a máa fúnni ní ìmọ́lẹ̀,a sì máa fi òye fún àwọn onírẹ̀lẹ̀. Mo la ẹnu, mò ń mí hẹlẹ,nítorí pé mò ń lépa òfin rẹ. Kọjú sí mi kí o ṣe mí lóorebí o ti máa ń ṣesí àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ. Mú ẹsẹ̀ mi dúró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ,má sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kankan jọba lórí mi. Gbà mí lọ́wọ́ ìnilára àwọn eniyan,kí n lè máa tẹ̀lé ìlànà rẹ. Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí ara èmi iranṣẹ rẹ;kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Omijé ń dà lójú mi pòròpòrò,nítorí pé àwọn eniyan kò pa òfin rẹ mọ́. Olódodo ni ọ́, OLUWA,ìdájọ́ rẹ sì tọ́. Òdodo ni o fi pa àṣẹ rẹ,òtítọ́ patapata ni. Mò ń tara gidigidi,nítorí pé àwọn ọ̀tá mi gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ. Mo láyọ̀ ninu pípa òfin rẹ mọ́,bí ẹni tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀. A ti yẹ ọ̀rọ̀ rẹ wò fínnífínní, ó dúró ṣinṣin,mo sì fẹ́ràn rẹ̀. Bí mo tilẹ̀ kéré, tí ayé sì kẹ́gàn mi,sibẹ n kò gbàgbé ìlànà rẹ. Òdodo rẹ wà títí lae,òtítọ́ sì ni òfin rẹ. Ìyọnu ati ìpayà dé bá mi,ṣugbọn mo láyọ̀ ninu òfin rẹ. Òdodo ni ìlànà rẹ títí lae,fún mi ní òye kí n lè wà láàyè. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ké pè ọ́,OLUWA, dá mi lóhùn;n óo sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ. Mo ké pè ọ́; gbà mí,n óo sì máa mú àṣẹ rẹ ṣẹ. Mo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́;mò ń retí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ. N kò fi ojú ba oorun ní gbogbo òru,kí n lè máa ṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ rẹ. Gbóhùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,OLÚWA, dá mi sí nítorí òtítọ́ rẹ. N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ,n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi súnmọ́ tòsí;wọ́n jìnnà sí òfin rẹ. Ṣugbọn ìwọ wà nítòsí, OLUWA,òtítọ́ sì ni gbogbo òfin rẹ. Ó pẹ́ tí mo ti kọ́ ninu ìlànà rẹ,pé o ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae. Wo ìpọ́njú mi, kí o gbà mí,nítorí n kò gbàgbé òfin rẹ. Gba ẹjọ́ mi rò, kí o sì gbà mí,sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn eniyan burúkú,nítorí wọn kò wá ìlànà rẹ. Àánú rẹ pọ̀, OLUWA,sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ rẹ. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi ati àwọn ọ̀tá mi pọ̀,ṣugbọn n kò yapa kúrò ninu ìlànà rẹ. Mò ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀ pẹlu ìríra,nítorí wọn kì í pa òfin rẹ mọ́. Wo bí mo ti fẹ́ ẹ̀kọ́ rẹ tó!Dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. N óo láyọ̀ ninu àwọn ìlànà rẹ,n kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ,gbogbo òfin òdodo rẹ ni yóo máa wà títí lae. Àwọn ìjòyè ń ṣe inúnibíni mi láìnídìí,ṣugbọn mo bẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ tọkàntọkàn. Mo láyọ̀ ninu ọ̀rọ̀ rẹ,bí ẹni pé mo ní ọpọlọpọ ìkógun. Mo kórìíra èké ṣíṣe, ara mi kọ̀ ọ́,ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ. Nígbà meje lojoojumọ ni mò ń yìn ọ́nítorí òfin òdodo rẹ. Alaafia ńláńlá ń bẹ fún àwọn tí ó fẹ́ràn òfin rẹ,kò sí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀. Mò ń retí ìgbàlà rẹ, OLUWA,mo sì ń pa àwọn òfin rẹ mọ́. Mò ń pa àṣẹ rẹ mọ́,mo fẹ́ràn wọn gidigidi. Mo gba ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ;gbogbo ìṣe mi ni ò ń rí. Jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ, OLUWA,fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ṣe ọpọlọpọ oore fún èmi iranṣẹ rẹ,kí n lè wà láàyè,kí n sì máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi dé iwájú rẹ,kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ẹnu mi yóo kún fún ìyìn rẹ,pé o ti kọ́ mi ní ìlànà rẹ. N óo máa fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe orin kọ,nítorí pé gbogbo òfin rẹ ni ó tọ̀nà. Múra láti ràn mí lọ́wọ́,nítorí pé mo ti gba ẹ̀kọ́ rẹ. Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, OLUWA;òfin rẹ sì ni inú dídùn mi. Dá mi sí kí n lè máa yìn ọ́,sì jẹ́ kí òfin rẹ ràn mí lọ́wọ́. Mo ti ṣìnà bí aguntan tó sọnù;wá èmi, iranṣẹ rẹ, rí,nítorí pé n kò gbàgbé òfin rẹ. Là mí lójú, kí n lè rí àwọn nǹkan ìyanutí ó wà ninu òfin rẹ. Àlejò ni mí láyé,má fi òfin rẹ pamọ́ fún mi. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́,tí wọn ń fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Òùngbẹ títẹ̀lé òfin rẹ ń gbẹ ọkàn mi, nígbà gbogbo. O bá àwọn onigbeeraga wí, àwọn ẹni ègún,tí wọn kò pa òfin rẹ mọ́. Mú ẹ̀gàn ati àbùkù wọn kúrò lára mi,nítorí pé mo ti pa òfin rẹ mọ́. Bí àwọn ìjòyè tilẹ̀ gbìmọ̀ràn ọ̀tẹ̀ nítorí mi,sibẹ, èmi iranṣẹ rẹ yóo ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ. Àwọn òfin rẹ ni dídùn inú mi,àwọn ni olùdámọ̀ràn mi. Mo di ẹni ilẹ̀,sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Nígbà tí mo jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe mi, o dá mi lóhùn;kọ́ mi ní ìlànà rẹ. La òfin rẹ yé mi,n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí iṣẹ́ ìyanu rẹ. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi nítorí ìbànújẹ́,mú mi lọ́kàn le gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Mú ìwà èké jìnnà sí mi,kí o sì fi oore ọ̀fẹ́ kọ́ mi ní òfin rẹ. Àwọn tí wọn kò dẹ́ṣẹ̀,ṣugbọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Mo ti yan ọ̀nà òtítọ́,mo ti fi ọkàn sí òfin rẹ. Mo pa òfin rẹ mọ́, OLUWA,má jẹ́ kí ojú ó tì mí. N óo yára láti pa òfin rẹ mọ́,nígbà tí o bá mú òye mi jinlẹ̀ sí i. OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ,n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin. Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́,kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́. Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ,nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀. Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ,kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé. Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán,sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ. Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ,àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ. Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò,nítorí pé ìlànà rẹ dára. O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́, Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ,sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ! Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA,kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn,nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá,nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ. N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae. N óo máa rìn fàlàlà,nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ. N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba,ojú kò sì ní tì mí. Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ,nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀. Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn,n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ. Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ,èyí tí ó fún mi ní ìrètí. Ìbá ti dára tótí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ! Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé:ìlérí rẹ mú mi wà láàyè. Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi,ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀. Mo ranti òfin rẹ àtijọ́,OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀. Inú mi á máa ru,nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú,tí wọn ń rú òfin rẹ. Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ,lákòókò ìrìn àjò mi láyé. Mo ranti orúkọ rẹ lóru;OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́: Èyí ni ìṣe mi:Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́. OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní;mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́. Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ,ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi,mo yipada sí ìlànà rẹ; Òun ni ojú kò fi ní tì mí,nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé. mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́. Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi,n kò ní gbàgbé òfin rẹ. Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́,nítorí ìlànà òdodo rẹ. Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí,àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́. OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;kọ́ mi ní ìlànà rẹ. OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ,gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé,nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ. Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ;ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ. OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe;kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀,ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́. N óo yìn ọ́ pẹlu inú mímọ́,bí mo ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo rẹ. Ọkàn wọn ti yigbì, ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ. Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani,ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ. Òfin rẹ níye lórí fún mi,ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ. Ìwọ ni o mọ mí, ìwọ ni o dá mi,fún mi ní òye kí n lè kọ́ òfin rẹ. Inú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yóo máa dùnnígbà tí wọ́n bá rí mi,nítorí pé mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. OLUWA, mo mọ̀ pé ìdájọ́ rẹ tọ̀nà,ati pé lórí ẹ̀tọ́ ni o pọ́n mi lójú. Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa tù mí ninu,gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe fún èmi, iranṣẹ rẹ. Ṣàánú mi, kí n lè wà láàyè,nítorí pé òfin rẹ ni ìdùnnú mi. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn onigbeeraga,nítorí wọ́n ṣe àrékérekè sí mi láìnídìí;ní tèmi, n óo máa ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ. Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ tọ̀ mí wá,kí wọ́n lè mọ òfin rẹ. N óo máa pa òfin rẹ mọ́,má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata. Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé,kí ojú má baà tì mí. Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi;ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ.Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?” Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì,sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ. Èmi iranṣẹ rẹ yóo ti dúró pẹ́ tó?Nígbà wo ni ìwọ óo dájọ́ fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi? Àwọn onigbeeraga ti gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,àní, àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́. Gbogbo òfin rẹ ló dájú;ràn mí lọ́wọ́, nítorí wọ́n ń fi ìwà èké ṣe inúnibíni mi. Wọ́n fẹ́rẹ̀ pa mí run láyé,ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀. Dá ẹ̀mí mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,kí n lè máa mú gbogbo àṣẹ rẹ ṣẹ. OLUWA, títí lae ni ọ̀rọ̀ rẹ fìdí múlẹ̀ lọ́run. Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́?Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni. Òtítọ́ rẹ wà láti ìrandíran;o ti fi ìdí ayé múlẹ̀, ó sì dúró. Ohun gbogbo wà gẹ́gẹ́ bí ìlànà rẹ, títí di òní,nítorí pé iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn. Bí kò bá jẹ́ pé òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi,ǹ bá ti ṣègbé ninu ìpọ́njú. Lae, n kò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ,nítorí pé, nípasẹ̀ wọn ni o fi mú mi wà láyé. Ìwọ ni o ni mí, gbà mí;nítorí pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ. Àwọn eniyan burúkú ba dè mí,wọ́n fẹ́ pa mí run,ṣugbọn mò ń ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ. Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán,àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin. Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ!Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru. Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo. Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ,nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò. Adura Ìrànlọ́wọ́. Gbani, OLUWA; nítorí àwọn olódodo kò sí mọ́;àwọn olóòótọ́ ti pòórá láàrin àwọn ọmọ eniyan. Olukuluku ń purọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀;ọ̀rọ̀ ìpọ́nni èké ati ẹ̀tàn ni wọ́n ń bá ara wọn sọ. Kí OLUWA pa gbogbo àwọn tí ń fi èké pọ́nni run, ati àwọn tí ń fọ́nnu, àwọn tí ń wí pé,“Ẹnu wa yìí ni a óo fi ṣẹgun,àwa la ni ẹnu wa; ta ni ó lè mú wa?” OLUWA wí pé, “Nítorí ìnira àwọn aláìṣẹ̀,ati nítorí ìkérora àwọn tí à ń pọ́n lójú,n óo dìde nisinsinyii,n óo sì dáàbò bò wọ́n bí ọkàn wọn ti ń fẹ́.” Ìlérí tó dájú ni ìlérí OLUWA,ó dàbí fadaka tí a yọ́ ninu iná ìléru amọ̀,tí a dà ninu iná nígbà meje. Dáàbò bò wá, OLUWA, pa wá mọ́ laelaekúrò lọ́wọ́ irú àwọn eniyan báwọ̀nyí. Àwọn eniyan burúkú ń yan kiri,níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan ń ṣe àpọ́nlé iṣẹ́ ibi. Adura Ìrànlọ́wọ́. OLUWA ni mo ké pè, nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú,ó sì dá mi lóhùn. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn èké,ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn. Kí ni a óo fi san án fun yín?Kí ni a óo sì ṣe si yín, ẹ̀yin ẹlẹ́tàn? Ọfà mímú ni a óo ta yín,a óo sì dáná sun yín. Mo gbé! Nítorí pé mo dàbí àlejò tó wọ̀ ní Meṣeki,tí ń gbé ààrin àwọn àgọ́ Kedari. Ó pẹ́ jù tí mo tí ń bá àwọn tí ó kórìíra alaafia gbé. Alaafia ni èmi fẹ́,ṣugbọn nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ìjà ṣá ni tiwọn. OLUWA Aláàbò Wa. Mo gbójú sókè wo àwọn òkè,níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá? Ìrànlọ́wọ́ mi ń ti ọ̀dọ̀ OLUWA wá,ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé. Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ó yẹ̀,ẹni tí ń pa ọ́ mọ́ kò ní tòògbé. Wò ó, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́kò ní tòògbé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sùn. OLUWA ni olùpamọ́ rẹ.OLUWA yóo ṣíji bò ọ́ ní apá ọ̀tún rẹ. Oòrùn kò ní ṣe ọ́ léṣe lọ́sàn-án,bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá kò ní pa ọ́ lára lóru. OLUWA óo dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ gbogbo ibi,yóo pa ọ́ mọ́. OLUWA yóo pa àlọ ati ààbọ̀ rẹ mọ́,láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae. Ìyìn Jerusalẹmu. Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé,“Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé OLUWA.” A ti tẹsẹ̀ bọ inú ìgboro rẹ, Jerusalẹmu. Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí a kọ́,tí gbogbo rẹ̀ já pọ̀ di ọ̀kan. Níbi tí àwọn ẹ̀yà,àní, àwọn ẹ̀yà eniyan OLUWA máa ń gòkè lọ,láti dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWAgẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí a pa fún Israẹli. Níbẹ̀ ni a tẹ́ ìtẹ́ ìdájọ́ sí,àní, ìtẹ́ ìdájọ́ àwọn ọba ìdílé Dafidi. Gbadura fún alaafia Jerusalẹmu!“Yóo dára fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ! Kí alaafia ó wà ninu rẹ,kí ìbàlẹ̀ àyà wà ninu ilé ìṣọ́ rẹ.” Nítorí ti àwọn ará ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi,n óo wí pé, “Kí alaafia ó wà ninu rẹ.” Nítorí ti ilé OLUWA, Ọlọrun wa,èmi óo máa wá ire rẹ. Adura Àánú. Ìwọ ni mo gbé ojú sókè sí,ìwọ tí o gúnwà ní ọ̀run. Wò ó, bí iranṣẹkunrin ti máa ń wo ojú oluwa rẹ̀,tí iranṣẹbinrin sì máa ń wo ojú oluwa rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni à ń wo ojú OLUWA, Ọlọrun wa,títí tí yóo fi ṣàánú wa. Ṣàánú wa, OLUWA, ṣàánú wa,ẹ̀gàn yìí ti pọ̀ jù! Ẹ̀gàn àwọn onírera ti pọ̀ jù fún wa;yẹ̀yẹ́ àwọn onigbeeraga sì ti sú wa. Ọlọrun Aláàbò Àwọn Eniyan Rẹ̀. Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wa,ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé, “Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wanígbà tí ọmọ aráyé gbógun tì wá, wọn ìbá gbé wa mì láàyè,nígbà tí inú bí wọn sí wa; àgbàrá ìbá ti gbá wa lọ,ìṣàn omi ìbá ti bò wá mọ́lẹ̀; ìgbì omi ìbá ti gbé wa mì.” Ọpẹ́ ni fún OLUWA,tí kò fi wá ṣe ẹran ìjẹ fún wọn. A ti yọ, bí ẹyẹ tí ó yọ ninu okùn apẹyẹ:okùn ti já; àwa sì ti yọ. Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìrànlọ́wọ́ wa ti wá,ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé. Ìfọ̀kànbalẹ̀ Àwọn Eniyan OLUWA. Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA dàbí òkè Sioni,tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí nídìí, ṣugbọn tí ó wà títí lae. Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yí àwọn eniyan rẹ̀ ká,láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae. Eniyan burúkú kò ní ní àṣẹlórí ilẹ̀ àwọn olódodo,kí àwọn olódodo má baà dáwọ́ lé ibi. OLUWA, ṣe oore fún àwọn eniyan rere,ati fún àwọn olódodo. Ṣugbọn OLUWA yóo fi irú ìyà àwọn aṣebi jẹàwọn tí ó yà sí ọ̀nà àìtọ́.Alaafia fún Israẹli! Ẹkún Di Ayọ̀. Nígbà tí OLUWA kó àwọn ìgbèkùn Sioni pada, ó dàbí àlá lójú wa. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ wa kún fún ẹ̀rín, a sì kọrin ayọ̀,nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń wí pé,“OLUWA mà ṣe nǹkan ńlá fún àwọn eniyan yìí!” Lóòótọ́, OLUWA ṣe nǹkan ńlá fún wa, nítorí náà à ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Dá ire wa pada, OLUWA,bí ìṣàn omi ní ipadò aṣálẹ̀ Nẹgẹbu. Àwọn tí ń fọ́n irúgbìn pẹlu omi lójú,jẹ́ kí wọn kórè rẹ̀ tayọ̀tayọ̀. Ẹni tí ń gbé irúgbìn lọ sí oko tẹkúntẹkún,yóo ru ìtí ọkà pada sílé tayọ̀tayọ̀. Abániṣé ni OLUWA. Bí OLUWA kò bá kọ́ ilé,asán ni wahala àwọn tí ń kọ́ ọ.Bí OLUWA kò bá ṣọ́ ìlú,asán ni àìsùn àwọn aṣọ́de. Asán ni kí á jí ní òwúrọ̀ kutukutu,kí á tún pẹ́ títí kí á tó sùn.Asán ni kí á máa fi làálàá wá oúnjẹ;nítorí pé OLUWA a máa fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ní oorun sùn. Wò ó! Ẹ̀bùn OLUWA ni ọmọ;òun ní fi oyún inú ṣìkẹ́ eniyan. Bí ọfà ti rí lọ́wọ́ jagunjagun,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà òwúrọ̀ ẹni. Ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí apó rẹ̀ kún fún wọn.Ojú kò ní tì í nígbà tí ó bá ń bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ rojọ́ lẹ́nu bodè. Ìbẹ̀rù OLUWA lérè. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLÚWA,tí ó sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀. O óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,ayọ̀ ń bẹ fún ọ, yóo sì dára fún ọ. Aya rẹ yóo dàbí àjàrà eléso pupọ ninu ilé rẹ;bí ọmọ tií yí igi olifi ká,ni àwọn ọmọ rẹ yóo yí tabili oúnjẹ rẹ ká. Wò ó, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo kẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Kí OLUWA bukun ọ láti Sioni!Kí o máa rí ire Jerusalẹmuní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Kí o máa rí arọmọdọmọ rẹ.Kí alaafia máa wà ní Israẹli. Kí ojú ti ọ̀tá. Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi.Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé, “Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi,sibẹ, wọn kò borí mi.” Wọ́n to ẹgba sí mi lẹ́yìn,gbogbo ẹ̀yìn mi lé bíi poro oko. Ṣugbọn olódodo ni OLUWA,ó ti gé okùn àwọn eniyan burúkú. Ojú yóo ti gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni,a óo lé wọn pada sẹ́yìn. Wọn óo dàbí koríko tí ó hù lórí òrùlé,tí kì í dàgbà kí ó tó gbẹ. Kò lè kún ọwọ́ ẹni tí ń pa koríko;kò sì lè kún ọwọ́ ẹni tí ń di koríko ní ìtí. Àwọn èrò ọ̀nà kò sì ní kí ẹni tí ń gé e pé:“OLUWA óo fèrè síṣẹ́ o!Ẹ kúuṣẹ́, OLUWA óo fèrè sí i.” Adura Ìrànlọ́wọ́. Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA?Ṣé o óo wá gbàgbé mi laelae ni?Títí di ìgbà wo ni o óo fi ojú pamọ́ fún mi? Títí di ìgbà wo ni ọkàn mi yóo gbọgbẹ́tí ìbànújẹ́ yóo gba ọkàn mi kan, ní gbogbo ìgbà?Títí di ìgbà wo ni àwọn ọ̀tá mi yóo máa yọ̀ mí? Bojúwò mí, kí o sì dá mi lóhùn, OLUWA, Ọlọrun mi.Tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú mi, kí n má baà sun oorun ikú. Kí ọ̀tá mi má baà wí pé, “Mo ti rẹ́yìn rẹ̀.”Kí àwọn tí ó kórìíra mi má baà yọ̀ bí mo bá ṣubú. Ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;n óo máa yọ̀ nítorí pé o óo gbà mí. N óo máa kọrin sí ọ, OLUWA,nítorí o ṣeun fún mi lọpọlọpọ. Adura Ẹlẹ́ṣẹ̀. Ninu ìṣòro ńlá ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA! OLUWA, gbóhùn mi,dẹtí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. Bí OLUWA bá ń sàmì ẹ̀ṣẹ̀,ta ló lè yege? Ṣugbọn ní ìkáwọ́ rẹ ni ìdáríjì wà,kí á lè máa bẹ̀rù rẹ. Mo gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, àní, mo gbé ọkàn mi lé e,mo sì ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀. Mò ń retí rẹ, OLUWA,ju bí àwọn aṣọ́de ti máa ń retí kí ilẹ̀ mọ́ lọ,àní, ju bí àwọn aṣọ́de, ti máa ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA!Nítorí pé ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ wà,ní ìkáwọ́ rẹ̀ sì ni ìràpadà kíkún wà. Òun óo sì ra Israẹli pada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Àṣírí ìfọ̀kànbalẹ̀. OLUWA, n kò ṣe ìgbéraga,bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè.N ò dáwọ́ lé nǹkan ńláńlá,n ò sì dá àrà tí ó jù mí lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi lọ́kàn balẹ̀, mo dákẹ́ jẹ́ẹ́,bí ọmọ ọwọ́ tíí dákẹ́ jẹ́ẹ́ láyà ìyá rẹ̀.Ọkàn mi balẹ̀ bíi ti ọmọ ọwọ́ tó dákẹ́ jẹ́ẹ́. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA,láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae. Majẹmu Ọlọrun pẹlu Ìdílé Dafidi. OLUWA, ranti gbogbo ìyà tí Dafidi fara dà. Nítorí ti Dafidi, iranṣẹ rẹ,má jẹ́ kí ẹni tí a fi òróró rẹ yàn yíjú kúrò lára rẹ. OLUWA ti ṣe ìbúra tí ó dájú fún Dafidi,èyí tí kò ní yipada; ó ní,“Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹni n óo gbé ka orí ìtẹ́ rẹ. Bí àwọn ọmọ rẹ bá pa majẹmu mi mọ́,tí wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí n óo fi lélẹ̀ fún wọn,àwọn ọmọ tiwọn náà óo jókòó lórí ìtẹ́ rẹ títí lae.” Nítorí OLUWA ti yan Sioni;ó fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀: Ó ní, “Ìhín ni ibi ìsinmi mi títí lae,níhìn-ín ni n óo máa gbé, nítorí pé ó wù mí. N óo bù sí oúnjẹ rẹ̀ lọpọlọpọ;n óo fi oúnjẹ tẹ́ àwọn aláìní ibẹ̀ lọ́rùn. N óo gbé ẹ̀wù ìgbàlà wọ àwọn alufaa rẹ̀,àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀ yóo sì kọrin ayọ̀. Níbẹ̀ ni n óo ti fún Dafidi ní agbára;mo ti gbé àtùpà kalẹ̀ fún ẹni tí mo fi òróró yàn. N óo da ìtìjú bo àwọn ọ̀tá rẹ̀ bí aṣọ,ṣugbọn adé orí rẹ̀ yóo máa tàn yinrinyinrin.” Ranti bí ó ṣe búra fún OLUWA,tí ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu, tí ó ní, “N kò ní wọ inú ilé mi,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní bọ́ sí orí ibùsùn mi; n kò ní sùn,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní tòògbé, títí tí n óo fi wá ààyè fún OLUWA,àní, tí n óo fi pèsè ibùgbé fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu.” A gbúròó rẹ̀ ní Efurata,a rí i ní oko Jearimu. “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùgbé rẹ̀;ẹ jẹ́ kí á lọ wólẹ̀ níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.” Dìde, OLUWA, lọ sí ibi ìsinmi rẹ,tìwọ ti àpótí agbára rẹ. Jẹ́ kí àwọn alufaa rẹ wọ ẹ̀wù òdodo,kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ sì máa kọrin ayọ̀. Ìrẹ́pọ̀ Àwọn ará. Ó dára, ó sì dùn pupọ,bí àwọn ará bá ń gbé pọ̀ ní ìrẹ́pọ̀. Ó dàbí òróró iyebíye tí a dà síni lórí,tí ó ṣàn dé irùngbọ̀n;bí ó ti ṣàn dé irùngbọ̀n Aaroni,àní, títí dé ọrùn ẹ̀wù rẹ̀. Ó dàbí ìrì òkè Herimoni,tí ó sẹ̀ sórí òkè Sioni.Níbẹ̀ ni OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun,àní, ìyè ainipẹkun. Ẹ yin OLUWA. Ẹ wá, ẹ yin OLUWA,gbogbo ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ń sìn ín ninu ilé rẹ̀ lóru. Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè, kí ẹ gbadura ninu ilé mímọ́ rẹ̀,kí ẹ sì yin OLUWA. Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayébukun yín láti Sioni wá. Orin Ìyìn. Ẹ yin OLUWA.Ẹ yin orúkọ OLUWA;ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, Ẹni tí ó pa orílẹ̀-èdè pupọ run;ó pa àwọn ọba alágbára: Sihoni ọba àwọn Amori,Ogu ọba Baṣani,ati gbogbo ọba ilẹ̀ Kenaani. Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀;ó pín in fún Israẹli bí ohun ìní wọn. OLUWA, orúkọ rẹ yóo wà títí lae,òkìkí rẹ óo sì máa kàn títí ayé. OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre,yóo sì ṣàánú àwọn iranṣẹ rẹ̀. Wúrà ati fadaka ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù fi ṣe oriṣa wọn,iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n. Wọ́n lẹ́nu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀,wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò lè ríran. Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò lè gbọ́ràn,bẹ́ẹ̀ ni kò sí èémí kan ní ẹnu wọn. Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóo dàbí wọn,ati gbogbo àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé wọn. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ yin OLUWA,ẹ̀yin ará ilé Aaroni, ẹ yin OLUWA! ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jọ́sìn ninu ilé OLUWA,tí ẹ wà ní àgbàlá ilé Ọlọrun wa. Ẹ̀yin ará ilé Lefi, ẹ yin OLUWA,ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ yìn ín! Ẹ yin OLUWA ní Sioni,ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu!Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA, nítorí pé ó ṣeun;ẹ kọrin ìyìn sí i,nítorí pé olóore ọ̀fẹ́ ni. Nítorí pé OLUWA ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀,ó ti yan Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀. Èmi mọ̀ pé OLUWA tóbi,ati pé ó ju gbogbo oriṣa lọ. Bí ó ti wu OLUWA ni ó ń ṣelọ́run ati láyé,ninu òkun ati ninu ibú. Òun ló gbá ìkùukùu jọ láti òpin ilẹ̀ ayé,ó fi mànàmáná fún òjò,ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀. Òun ló pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti,ati teniyan ati tẹran ọ̀sìn. Ẹni tí ó rán iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu sí ilẹ̀ Ijipti,ó rán sí Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀. Orin Ọpẹ́. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láàrin wọn,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Pẹlu ipá ati ọwọ́ líle ni ó fi kó wọn jáde,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó pín Òkun Pupa sí meji,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli kọjá láàrin rẹ̀,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ṣugbọn ó bi Farao ati àwọn ọmọ ogunrẹ̀ ṣubú ninu Òkun Pupa,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó mú àwọn eniyan rẹ̀ la aṣálẹ̀ já,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ẹni tí ó pa àwọn ọba ńlá,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì pa àwọn ọba olókìkí,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; Sihoni ọba àwọn Amori,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí ó ju gbogbo àwọn oriṣa lọ,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. ati Ogu ọba Baṣani,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó fún àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ̀,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Òun ni ó ranti wa ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ wa,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó pèsè oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá alààyè,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun ọ̀run,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tí ó ju gbogbo àwọn oluwa lọ,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Òun nìkan ṣoṣo ní ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lé orí omi,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó dá oòrùn láti máa ṣe àkóso ọ̀sán,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó dá òṣùpá ati ìràwọ̀ láti máa ṣe àkóso òru,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Àwọn Ọmọ Israẹli Kọrin Arò ní Ìgbèkùn. Lẹ́bàá odò Babiloni ni a jókòó, tí a sọkún,nígbà tí a ranti Sioni. Lára igi wilo níbẹ̀ ni a fi hapu wa kọ́ sí, nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùnti ní kí á kọrin fún àwọn.Àwọn tí ó ń pọ́n wa lójú sọ pé kí á dá àwọn lárayá, wọ́n ní,“Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.” Báwo ni a óo ṣe kọ orin OLUWA ní ilẹ̀ àjèjì? Jerusalẹmu, bí mo bá gbàgbé rẹ,kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó rọ. Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ èrìgì mi,bí n kò bá ranti rẹ,bí n kò bá sì fi Jerusalẹmu ṣe olórí ayọ̀ mi. OLUWA, ranti ohun tí àwọn ará Edomu ṣenígbà tí Jerusalẹmu bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá,tí wọn ń pariwo pé,“Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀.” Babiloni! Ìwọ apanirun!Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ̀san lára rẹ,fún gbogbo ohun tí o ti ṣe sí wa! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá kó àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ,tí ó ṣán wọn mọ́ àpáta. Adura Ọpẹ́. N óo máa yìn ọ́ tọkàntọkàn OLUWA,lójú àwọn oriṣa ni n óo máa kọrin ìyìn sí ọ. Ní ìtẹríba, n óo kọjú sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ,n óo sì máa yin orúkọ rẹ,nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ,nítorí pé o gbé ọ̀rọ̀ rẹ ati orúkọ rẹ ga ju ohunkohun lọ. Ní ọjọ́ tí mo ké pè ọ́, o dá mi lóhùn,o sì fún mi ní agbára kún agbára. OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo máa yìn ọ́,nítorí pé wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Wọn óo sì máa kọrin nípa iṣẹ́ OLUWA,nítorí pé ògo OLUWA tóbi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ga lọ́lá,ó ka àwọn onírẹ̀lẹ̀ sí,ṣugbọn ó mọ àwọn onigbeeraga lókèèrè. Bí mo tilẹ̀ wà ninu ìpọ́njú,sibẹ, o dá mi sí;o dojú ìjà kọ ibinu àwọn ọ̀tá mi,o sì fi ọwọ́ agbára rẹ gbà mí. OLUWA yóo mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí mi,OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.Má kọ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sílẹ̀. Ọlọrun Olùmọ̀ràn Ọkàn. OLUWA, o ti yẹ̀ mí wò, o sì mọ̀ mí. níbẹ̀ gan-an, ọwọ́ rẹ ni yóo máa tọ́ mi,tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo sì dì mí mú. Bí mo bá wí pé kí kìkì òkùnkùn bò mí mọ́lẹ̀,kí ọ̀sán di òru fún mi, òkùnkùn gan-an kò ṣú jù fún ọ;òru mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;lójú rẹ, ìmọ́lẹ̀ kò yàtọ̀ sí òkùnkùn. Nítorí ìwọ ni o dá inú mi,ìwọ ni o sọ mí di odidi ní inú ìyá mi. Mo yìn ọ́, nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati ẹni ìyanu ni ọ́;ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!O mọ̀ mí dájú. Nígbà tí à ń ṣẹ̀dá egungun mi lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀,tí ẹlẹ́dàá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣọnà sí mi lára ní àṣírí,kò sí èyí tí ó pamọ́ fún ọ. Kí á tó dá mi tán ni o ti rí mi,o ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún misinu ìwé rẹ,kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá. Ọlọrun, iyebíye ni èrò rẹ lójú mi!Wọ́n pọ̀ pupọ ní iye. Bí mo bá ní kí n kà wọ́n,wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ;nígbà tí mo bá sì jí,ọ̀dọ̀ rẹ náà ni n óo wà. Ọlọrun, ò bá jẹ́ pa àwọn eniyan burúkú,kí àwọn apànìyàn sì kúrò lọ́dọ̀ mi. O mọ ìgbà tí mo jókòó, ati ìgbà tí mo dìde;o mọ èrò ọkàn mi láti òkèèrè réré. Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ nípa rẹ,àwọn ọ̀tá rẹ ń ba orúkọ rẹ jẹ́. OLUWA, mo kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ;mo sì kẹ́gàn àwọn tí ń dìtẹ̀ sí ọ? Mo kórìíra wọn dé òpin;ọ̀tá ni mo kà wọ́n kún. Wádìí mi, Ọlọrun, kí o mọ ọkàn mi;yẹ̀ mí wò, kí o sì mọ èrò ọkàn mi. Wò ó bí ọ̀nà ibi kan bá wà tí mò ń tọ̀,kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà ayérayé. O yẹ ìrìn ẹsẹ̀ mi ati àbọ̀sinmi mi wò;gbogbo ọ̀nà mi ni o sì mọ̀. Kódà kí n tó sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu,OLUWA, o ti mọ gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ sọ patapata. O pa mí mọ́, níwájú ati lẹ́yìn;o gbé ọwọ́ ààbò rẹ lé mi. Irú ìmọ̀ yìí jẹ́ ohun ìyanu fún mi,ó ga jù, ojú mi kò tó o. Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí rẹ kò ní sí níbẹ̀?Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú rẹ kò ní tó mi? Ǹ báà gòkè re ọ̀run, o wà níbẹ̀!Bí mo sì tẹ́ ibùsùn mi sí isà òkú, n óo bá ọ níbẹ̀. Ǹ báà hu ìyẹ́, kí n fò lọ sí ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wá,kí n lọ pàgọ́ sí ibi tí òkun pin sí, Èrè Òmùgọ̀. Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò sí.”Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn,kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere. OLUWA bojú wo ilẹ̀, láti ọ̀run wá,ó wo àwọn ọmọ eniyan,láti mọ̀ bí àwọn kan bá wà tí wọ́n gbọ́n,tí wọn ń wá Ọlọrun. Gbogbo wọn ti ṣìnà,gbogbo wọn pátá ni wọ́n sì ti bàjẹ́;kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere,kò sí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo. Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni?Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun,àwọn tí kì í ké pe OLUWA. Níbẹ̀ ni a óo ti dẹ́rù bà wọ́n gidigidi,nítorí Ọlọrun ń bẹ pẹlu àwọn olódodo. Ẹ̀yin ń fẹ́ da ètò aláìní rú,ṣugbọn OLUWA ni ààbò rẹ̀. Ìbá ti dára tó kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá!Nígbà tí OLUWA bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada,Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn. Adura Ààbò. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi;dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá; Jẹ́ kí ẹ̀yinná dà lé wọn lórí;jẹ́ kí wọn já sí kòtò, kí wọn má lè yọ. Má jẹ́ kí abanijẹ́ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ilẹ̀ náà;jẹ́ kí oníwà ipá ko àgbákò kíákíá. Mo mọ̀ pé OLUWA yóo gba ọ̀ràn olùpọ́njú rò,yóo sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní. Dájúdájú, àwọn olódodo yóo máa fi ọpẹ́ fún ọ;àwọn olóòótọ́ yóo sì máa gbé níwájú rẹ. àwọn tí ó ń pète ibi lọ́kàn wọn,tí wọ́n sì ń dá ogun sílẹ̀ nígbàkúùgbà, Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn, ó mú bí ahọ́n ejò;oró paramọ́lẹ̀ sì ń bẹ ninu eyín wọn. OLUWA, ṣọ́ mi lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú;dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá,tí ó ń gbìmọ̀ láti ré mi lẹ́pa. Àwọn agbéraga ti dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí,wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi;wọ́n sì dẹ okùn sílẹ̀ fún mi lẹ́bàá ọ̀nà. Mo wí fún OLUWA pé, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.”OLUWA, tẹ́tí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. OLUWA, OLUWA mi, alágbára tíí gbani là,ìwọ ni o dáàbò bò mí ní ọjọ́ ogun. OLUWA, má jẹ́ kí ọwọ́ àwọn eniyan burúkú tẹ ohun tí wọn ń wá;má jẹ́ kí èrò ọkàn wọn ṣẹ. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ibi ẹnu àwọn tí ó yí mi kádà lé wọn lórí. Adura Ààbò. OLUWA, mo ké pè ọ́, tètè wá dá mi lóhùn,tẹ́tí sí ohùn mi nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́. Jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú ṣubú sinu àwọ̀n ara wọn,kí èmi sì lọ láìfarapa. Jẹ́ kí adura mi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ bíi turari,sì jẹ́ kí ọwọ́ adura tí mo gbé sókè dàbí ẹbọ àṣáálẹ́. OLUWA, fi ìjánu sí mi ní ẹnu,sì ṣe aṣọ́nà ètè mi. Má jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ibi, má sì jẹ́ kí n lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkà.Má jẹ́ kí n bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rìn pọ̀,má sì jẹ́ kí n jẹ ninu oúnjẹ àdídùn wọn. N ò kọ̀ kí ẹni rere bá mi wí,n ò kọ̀ kí ó nà mí;kí ó ṣá ti fi ìfẹ́ bá mi wí.Ṣugbọn má jẹ́ kí eniyan burúkú tilẹ̀ ta òróró sí mi lórí,nítorí pé nígbàkúùgbà ni mò ń fi adura tako ìwà ibi wọn. Nígbà tí ọwọ́ àwọn tí yóo dá wọn lẹ́bi bá tẹ̀ wọ́n,wọn óo gbà pé, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA. Bí òkúta tí eniyan là, tí ó fọ́ yángá-yángá sílẹ̀,ni a óo fọ́n egungun wọn ká sí ẹnu ibojì. Ṣugbọn ìwọ ni mo gbójúlé, OLUWA, Ọlọrun.Ìwọ ni asà mi,má fi mí sílẹ̀ láìní ààbò. Pa mí mọ́ ninu ewu tàkúté,ati ti okùn tí àwọn aṣebi dẹ sílẹ̀ dè mí. Adura Ìrànlọ́wọ́ . Mo ké pe OLUWA,mo gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè sí i. Mo tú ẹ̀dùn ọkàn mi palẹ̀ níwájú rẹ̀,mo sọ ìṣòro mi fún un. Nígbà tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì,ó mọ ọ̀nà tí mo lè gbà.Wọ́n ti dẹ tàkúté sílẹ̀ fún miní ọ̀nà tí mò ń rìn. Mo wo ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún mi yíká,mo rí i pé kò sí ẹni tí ó náání mi;kò sí ààbò fún mi,ẹnikẹ́ni kò sì bìkítà fún mi. Mo ké pè ọ́, OLUWA,mo ní, “Ìwọ ni ààbò mi,ìwọ ni ìpín mi lórí ilẹ̀ alààyè.” Gbọ́ igbe mi;nítorí wọ́n ti rẹ̀ mí sílẹ̀ patapata.Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi,nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ. Yọ mí kúrò ninu ìhámọ́,kí n lè yin orúkọ rẹ lógo.Àwọn olódodo yóo yí mi ká,nítorí ọpọlọpọ oore tí o óo ṣe fún mi. Adura Ìrànlọ́wọ́. OLUWA, gbọ́ adura mi;fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi!Dá mi lóhùn ninu òtítọ́ ati òdodo rẹ. Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ,nítorí pé ìwọ ni Ọlọrun mi.Jẹ́ kí ẹ̀mí rere rẹ máa tọ́ mi ní ọ̀nà tí ó tọ́. Nítorí ti orúkọ rẹ, OLUWA, dá mi sí;ninu òtítọ́ rẹ, yọ mí ninu ìpọ́njú. Ninu ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, pa àwọn ọ̀tá mi,kí o sì pa gbogbo àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi run,nítorí pé iranṣẹ rẹ ni mí. Má dá èmi ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lẹ́jọ́,nítorí pé kò sí ẹ̀dá alààyè tí ẹjọ́ rẹ̀ lè tọ́ níwájú rẹ. Ọ̀tá ti lé mi bá,ó ti lù mí bolẹ̀;ó jù mí sinu òkùnkùn,bí ẹni tí ó ti kú tipẹ́tipẹ́. Nítorí náà ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì;ọkàn mi sì pòrúúruù. Mo ranti ìgbà àtijọ́,mo ṣe àṣàrò lórí gbogbo ohun tí o ti ṣe,mo sì ronú lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Mo na ọwọ́ sí ọ fún ìrànlọ́wọ́;bí òùngbẹ omi í tií gbẹ ilẹ̀ gbígbẹ,bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi. OLUWA, yára dá mi lóhùn!Ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ pin!Má fara pamọ́ fún mi,kí n má baà dàbí àwọn tí ó ti lọ sinu isà òkú. Jẹ́ kí n máa ranti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ láràárọ̀,nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.Kọ́ mi ní ọ̀nà tí n óo máa rìn,nítorí pé ìwọ ni mo gbójú sókè sí. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;ìwọ ni mo sá di. Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun. Ìyìn ni fún OLUWA, àpáta mi,ẹni tí ó kọ́ mi ní ìjà jíjà,tí ó kọ́ mi ní iṣẹ́ ogun. Ìwọ ni ò ń fún àwọn ọba ní ìṣẹ́gun,tí o sì gba Dafidi, iranṣẹ rẹ, là. Gbà mí lọ́wọ́ idà ìkà,gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,tí ẹnu wọ́n kún fún irọ́,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké. Ní ìgbà èwe àwọn ọdọmọkunrin wa,jẹ́ kí wọ́n dàbí igi tí a gbìn tí ó dàgbà,kí àwọn ọdọmọbinrin wa dàbí òpó igun ilé,tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí bíi ti ààfin ọba. Kí àká wa kún fún oniruuru oúnjẹ,kí àwọn aguntan wa bí ẹgbẹẹgbẹrun,àní, ẹgbẹẹgbaarun ninu pápá oko wa. Kí àwọn mààlúù wa lóyún,kí wọ́n má rọ́nú, kí wọ́n má bí òkúmọ;kí ó má sí ariwo àjálù ní ìgboro wa. Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí ó ní irú ibukun yìí;ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn. Òun ni àpáta mi, ààbò mi, odi mi, olùdáǹdè mi,asà mi, ẹni tí mo sá di.Òun ni ó tẹrí àwọn eniyan ba lábẹ́ rẹ̀. OLUWA, kí ni eniyan jẹ́, tí o fi ń náání rẹ̀?Kí sì ni ọmọ eniyan tí o fi ń ranti rẹ̀? Eniyan dàbí èémí,ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí òjìji tí ń kọjá lọ. OLUWA, fa ojú ọ̀run wá sílẹ̀, kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,fọwọ́ kan àwọn òkè ńlá, kí wọ́n máa rú èéfín. Jẹ́ kí mànàmáná kọ, kí o sì tú wọn ká,ta ọfà rẹ, kí o tú wọn ká. Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti òkè,kí o yọ mí ninu ibú omi;kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì, tí ẹnu wọn kún fún irọ́,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké. Ọlọrun, n óo kọ orin titun sí ọ,n óo fi hapu olókùn mẹ́wàá kọrin sí ọ. Orin Ìyìn. Èmi óo gbé ọ ga, Ọlọrun mi, Ọba mi,n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae. OLUWA, gbogbo ohun tí o dá ni yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ,àwọn eniyan mímọ́ rẹ yóo sì máa yìn ọ́. Wọn óo máa ròyìn ògo ìjọba rẹ,wọn óo sì máa sọ nípa agbára rẹ, láti mú àwọn eniyan mọ agbára rẹ,ati ẹwà ògo ìjọba rẹ. Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ,yóo sì máa wà láti ìran dé ìran.Olóòótọ́ ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀,olóore ọ̀fẹ́ sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀. OLUWA gbé gbogbo àwọn tí ń ṣubú lọ dìde,ó sì gbé gbogbo àwọn tí a tẹrí wọn ba nàró. Ojú gbogbo eniyan ń wò ọ́,o sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò. Ìwọ la ọwọ́ rẹ,o sì tẹ́ gbogbo ẹ̀dá alààyè lọ́rùn. Olódodo ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀nà rẹ̀,aláàánú sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀. OLUWA súnmọ́ gbogbo àwọn tí ń pè é,àní, àwọn tí ń pè é tọkàntọkàn. Ó ń tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ lọ́rùn;ó ń gbọ́ igbe wọn, ó sì ń gbà wọ́n. Lojoojumọ ni n óo máa yìn ọ́,tí n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae. OLUWA dá gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ẹ sí,ṣugbọn yóo pa gbogbo àwọn eniyan burúkú run. Ẹnu mi yóo máa sọ̀rọ̀ ìyìn OLUWA;kí gbogbo ẹ̀dá máa yin orúkọ rẹ̀ lae ati laelae. OLUWA tóbi, ìyìn sì yẹ ẹ́ lọpọlọpọ;àwámárìídìí ni títóbi rẹ̀. Láti ìran dé ìran ni a óo máa yin iṣẹ́ rẹ,tí a óo sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ agbára ńlá rẹ. Èmi óo máa ṣe àṣàrò lórí ẹwà ògo ọlá ńlá rẹ,ati iṣẹ́ ìyanu rẹ. Eniyan óo máa kéde iṣẹ́ agbára rẹ tí ó yani lẹ́nu,èmi óo sì máa polongo títóbi rẹ. Wọn óo máa pòkìkí bí oore rẹ ti pọ̀ tó,wọn óo sì máa kọrin sókè nípa òdodo rẹ. Aláàánú ni OLUWA, olóore sì ni;kì í yára bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀. OLUWA ṣeun fún gbogbo eniyan,àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo ohun tí ó dá. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ẹ yin OLUWA!Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi. OLUWA yóo jọba títí lae,Sioni, Ọlọrun rẹ yóo jọba láti ìran dé ìran.Ẹ yin OLUWA. N óo máa yin OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo wà láyé;n óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè. Má gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè;eniyan ni wọ́n, kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ wọn. Bí ẹ̀mí wọn bá ti bọ́, wọn á pada di erùpẹ̀,ní ọjọ́ náà sì ni èrò inú wọn óo di ègbé. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó fi Ọlọrun Jakọbu ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ̀,tí ó gbójú lé OLUWA, Ọlọrun rẹ̀. Ọlọrun tí ó dá ọ̀run ati ayé,òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀;Ọlọrun tíí máa ń pa àdéhùn rẹ̀ mọ́ títí lae, ẹni tíí máa ń dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn tí a ni lára;tí ń fún àwọn tí ebi ń pa ní oúnjẹ,OLUWA tíí tú àwọn tí ó wà ninu ìdè sílẹ̀. A máa la ojú àwọn afọ́jú,a máa gbé àwọn tí a tẹrí wọn ba dúró;ó fẹ́ràn àwọn olódodo. OLUWA ni olùṣọ́ àwọn àlejò,òun ni alátìlẹ́yìn àwọn opó ati aláìníbaba,ṣugbọn a máa da ète àwọn eniyan burúkú rú. Ọlọrun Alágbára. Ẹ yin OLUWA!Nítorí tí ó dára láti máa kọ orin ìyìn sí Ọlọrun wa;nítorí olóore ni, orin ìyìn sì yẹ ẹ́. Kì í ṣe agbára ẹṣin ni inú rẹ̀ dùn sí,kì í sì í ṣe inú agbára eniyan ni ayọ̀ rẹ̀ wà. Ṣugbọn inú OLUWA dùn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àwọn tí ó ní ìrètí ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Gbé OLUWA ga, ìwọ Jerusalẹmu!Yin Ọlọrun rẹ, ìwọ Sioni! Ó fún ẹnubodè rẹ ní agbára,ó sì bukun àwọn tí ń gbé inú rẹ. Ó jẹ́ kí alaafia wà ní ààlà ilẹ̀ rẹ,ó sì fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ ọ lábọ̀ọ́yó. Ó pàṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,àṣẹ rẹ̀ sì múlẹ̀ kíá. Ó da òjò dídì bo ilẹ̀ bí ẹ̀gbọ̀n òwú,ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú. Ó sọ yìnyín sílẹ̀ bí òkò,ta ni ó lè fara da òtútù rẹ̀? Ó sọ̀rọ̀, wọ́n yọ́,ó fẹ́ afẹ́fẹ́, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn. Ó ṣí ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá fún Jakọbu,ó sì fi òfin ati ìlànà rẹ̀ han Israẹli. OLUWA ní ń kọ́ ìlú Jerusalẹmu;òun ni yóo kó àwọn ọmọ Israẹli tí a fọ́n ká jọ. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè kankan rí,wọn kò sì mọ ìlànà rẹ̀.Ẹ yin OLUWA! Ó ń tu àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́ ninu,ó sì ń dí ọgbẹ́ wọn. Òun ló mọ iye àwọn ìràwọ̀,òun ló sì fún gbogbo wọn lórúkọ. OLUWA wa tóbi, ó sì lágbára pupọòye rẹ̀ kò ní ìwọ̀n. OLUWA ní ń gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ró,òun ni ó sì ń sọ àwọn eniyan burúkú di ilẹ̀ẹ́lẹ̀. Ẹ kọ orin ọpẹ́ sí OLUWA,ẹ fi hapu kọ orin dídùn sí Ọlọrun wa. Ẹni tí ó fi ìkùukùu bo ojú ọ̀run,ó pèsè òjò fún ilẹ̀,ó mú koríko hù lórí òkè. Òun ni ó ń fún àwọn ẹranko ní oúnjẹ,tí ó sì ń bọ́ ọmọ ẹyẹ ìwò, tí ó ń ké. Kí gbogbo ẹ̀dá Yin OLUWA. Ẹ yin OLUWA!Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,ẹ yìn ín lókè ọ̀run. ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ ati ẹran ọ̀sìn,ẹ̀yin ẹ̀dá tí ń fàyà fà ati ẹyẹ tí ń fò. Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọba ayé ati gbogbo orílẹ̀-èdè,ẹ̀yin ìjòyè ati gbogbo onídàájọ́ ayé; ẹ̀yin ọdọmọkunrin ati ọlọ́mọge,ẹ̀yin ọmọde ati ẹ̀yin àgbààgbà. Ẹ jẹ́ kí wọn yin orúkọ OLUWA,nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ga jù;ògo rẹ̀ sì ga ju ayé ati ọ̀run lọ. Ó ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára,ó sì fún àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ ní ìyìn;ó fún àwọn eniyan Israẹli, tí ó wà lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ̀.Ẹ yin OLUWA! Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀;ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀. Ẹ yìn ín, oòrùn ati òṣùpá;ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ tí ń tàn. Ẹ yìn ín, ọ̀run tí ó ga jùlọ;yìn ín, omi tí ó wà lójú ọ̀run. Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa yin orúkọ OLUWA,nítorí nípa àṣẹ rẹ̀ ni a fi dá wọn. Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ títí laelae;ó sì pààlà fún wọn tí wọn kò gbọdọ̀ ré kọjá. Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ayé,ẹ̀yin erinmi ńláńlá inú òkun ati gbogbo ibú omi; iná ati yìnyín, ati ìrì dídì,ati ẹ̀fúùfù líle tí ń mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ. Ẹ yìn ín, ẹ̀yin òkè ńláńlá ati òkè kéékèèké,ẹ̀yin igi eléso ati igi kedari; Orin Ìyìn sí OLUWA. Ẹ yin OLUWA!Ẹ kọ orin titun sí OLUWA,ẹ kọrin ìyìn sí i ninu àwùjọ àwọn olóòótọ́. Kí Israẹli máa yọ̀ ninu Ẹlẹ́dàá rẹ̀,kí àwọn ọmọ Sioni máa fò fún ayọ̀ pé àwọn ní Ọba. Kí wọn máa fi ijó yin orúkọ rẹ̀,kí wọn máa fi ìlù ati hapu kọ orin aládùn sí i. Nítorí pé inú OLUWA dùn sí àwọn eniyan rẹ̀,a sì máa fi ìṣẹ́gun dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé. Kí àwọn olódodo máa ṣògo ninu ọlá;kí wọ́n máa kọrin ayọ̀ lórí ibùsùn wọn. Kí wọn máa fi ohùn wọn yin Ọlọrun;kí idà olójú meji sì wà ní ọwọ́ wọn, láti gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ati láti jẹ àwọn eniyan wọn níyà; láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba orílẹ̀-èdè mìíràn,ati láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn ọlọ́lá wọn; láti ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀.Ògo gbogbo àwọn olódodo nìyí. Ẹ yin OLUWA! Ìwà tí Ọlọrun Fẹ́. OLUWA, ta ni ó lè máa gbé inú àgọ́ rẹ?Ta ni ó lè máa gbé orí òkè mímọ́ rẹ? Ẹni tí ń rìn déédéé, tí ń ṣe òdodo;tí sì ń fi tọkàntọkàn sọ òtítọ́. Ẹni tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn,tí kò ṣe ibi sí ẹnìkejì rẹ̀,tí kò sì sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nípa aládùúgbò rẹ̀. Ẹni tí kò ka ẹni ẹ̀kọ̀ sí,ṣugbọn a máa bu ọlá fún àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA;bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́, kì í yẹ̀ ẹ́;bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti wù kí ó nira tó. Kì í yáni lówó kí ó gba èlé,kìí sìí gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ aláìṣẹ̀.Ẹni tí ó bá ṣe nǹkan wọnyi,ẹsẹ̀ rẹ̀ kò ní yẹ̀ laelae. Ẹ yin OLUWA. Ẹ yin OLUWA!Ẹ yin Ọlọrun ninu ibi mímọ́ rẹ̀;ẹ yìn ín ninu òfuurufú rẹ̀ tí ó lágbára. Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀;ẹ yìn ín nítorí pé ó tóbi pupọ. Ẹ fi ariwo fèrè yìn ín;ẹ fi fèrè ati hapu yìn ín. Ẹ fi ìlù ati ijó yìn ín;ẹ fi gòjé ati dùùrù yìn ín. Ẹ fi aro olóhùn òkè yìn ín;ẹ fi aro olóhùn gooro yìn ín. Kí gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA! Mo Sá di OLUWA. Pa mí mọ́ Ọlọrun, nítorí ìwọ ni mo sá di. Nítorí o kò ní gbàgbé mi sí ipò òkú,bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni tí ó fi tọkàntọkàn sìn ọ́ rí ìdíbàjẹ́. O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí;ayọ̀ kíkún ń bẹ ní iwájú rẹ,ìgbádùn àìlópin sì ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ. Mo wí fún ọ, OLUWA, pé, “Ìwọ ni Oluwa mi;ìwọ nìkan ni orísun ire mi.” Nípa àwọn eniyan mímọ́ tí ó wà nílẹ̀ yìí,wọ́n jẹ́ ọlọ́lá tí àwọn eniyan fẹ́ràn. “Ìbànújẹ́ àwọn tí ń sá tọ ọlọrun mìíràn lẹ́yìn yóo pọ̀:Èmi kò ní bá wọn ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ fún ìrúbọ,bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu mi.” OLUWA, ìwọ ni ìpín mi, ìwọ ni mo yàn;ìwọ ni ò ń jẹ́ kí ọ̀ràn mi fìdí múlẹ̀. Ìpín tí ó bọ́ sí mi lọ́wọ́ dára pupọ;ogún rere ni ogún ti mo jẹ. Èmi óo máa yin OLUWA, ẹni tí ó ń fún mi ní òye;ọkàn mi ó sì máa tọ́ mi sọ́nà ní òròòru. Mò ń wo OLUWA ní iwájú mi nígbà gbogbo,nítorí pé Ọlọrun dúró tì mí, ẹsẹ̀ mi kò ní yẹ̀. Nítorí náà ni ọkàn mi ṣe ń yọ̀, tí inú mi dùn;ara sì rọ̀ mí. Adura fún Ìdáláre. Gbọ́ tèmi OLUWA, àre ni ẹjọ́ mi; fi ìtara gbọ́ igbe mi.Fetí sí adura mi nítorí kò sí ẹ̀tàn ní ẹnu mi. Ojú àánú wọn ti fọ́,ọ̀rọ̀ ìgbéraga sì ń ti ẹnu wọn jáde. Wọn ń lépa mi; wọ́n sì ti yí mi ká báyìí;wọn ń ṣọ́ bí wọn ó ṣe bì mí ṣubú. Wọ́n dàbí kinniun tí ó ṣetán láti pa ẹran jẹ,àní bí ọmọ kinniun tí ó ba ní ibùba. Dìde, OLUWA! Dojú kọ wọ́n; là wọ́n mọ́lẹ̀;fi idà rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú. OLUWA, fi ọwọ́ ara rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan wọnyi;àwọn tí ìpín wọn jẹ́ ohun ti ayé yìí,fi ohun rere jíǹkí àwọn ẹni tí o pamọ́;jẹ́ kí àwọn ọmọ jẹ àjẹyó;sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ọmọ wọn rí ogún wọn jẹ. Ní tèmi, èmi óo rí ojú rẹ nítorí òdodo mi,ìrísí rẹ yóo sì tẹ́ mi lọ́rùn nígbà tí mo bá jí. Jẹ́ kí ìdáláre mi ti ọ̀dọ̀ rẹ wá;kí o sì rí i pé ẹjọ́ mi tọ́. Yẹ ọkàn mi wò; bẹ̀ mí wò lóru.Dán mi wò, o kò ní rí ohun burúkú kan;n kò ní fi ẹnu mi dẹ́ṣẹ̀. Nítorí ohun tí o wí nípa èrè iṣẹ́ ọwọ́ eniyan,mo ti yàgò fún àwọn oníwà ipá. Mò ń tọ ọ̀nà rẹ tààrà;ẹsẹ̀ mi kò sì yọ̀. Mo ké pè ọ́, dájúdájú ìwọ Ọlọrun yóo dá mi lóhùn,dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn lọ́nà ìyanu,fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọkúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì wọ́n. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú,dáàbò bò mí lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ; lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú tí ó gbé ìjà kò mí,àní lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká. Orin Ìṣẹ́gun. Mo fẹ́ràn rẹ, OLUWA, agbára mi. Ó gun orí Kerubu, ó sì fò,ó fò lọ sókè lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́. Ó fi òkùnkùn bora bí aṣọ,ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omini ó fi ṣe ìbòrí. Ninu ìmọ́lẹ̀ níwájú rẹ,ẹ̀yinná ati yìnyín ń fọ́n jáde,láti inú ìkùukùu. OLUWA sán ààrá láti ọ̀run,Ọ̀gá Ògo fọhùn, òjò dídì ati ẹ̀yinná sì fọ́n jáde. Ó ta ọfà rẹ̀ jáde, ó sì fọ́n wọn ká,ó jẹ́ kí mànàmáná kọ, ó sì tú wọn ká. Nígbà náà ni ìsàlẹ̀ òkun hàn ketekete,ìpìlẹ̀ ayé sì fojú hàn gbangba nítorí ìbáwí rẹ, OLUWA,ati nítorí agbára èémí ihò imú rẹ. Ó nawọ́ láti òkè wá, ó sì dì mí mú,ó fà mí jáde láti inú ibú omi. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi tí ó lágbára,ati lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi;nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ. Wọ́n gbógun tì mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi,ṣugbọn OLUWA ni aláfẹ̀yìntì mi. Ó mú mi jáde wá síbi tí ó láàyè,ó yọ mí jáde nítorí tí inú rẹ̀ dùn sí mi. OLUWA ni àpáta mi, ibi ààbò mi, ati olùgbàlà mi;Ọlọrun mi, àpáta mi, ninu ẹni tí ààbò mi wà.Òun ni asà mi, ìwo ìgbàlà mi ati ibi ìsásí mi. OLUWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ ni ó ṣe pín mi lérè. Nítorí tí mo ti pa ọ̀nà OLUWA mọ́,n kò ṣe ibi nípa yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi. Nítorí pé gbogbo òfin rẹ̀ ni mo tẹ̀lé,n kò sì yà kúrò ninu ìlànà rẹ̀. Mo wà ní àìlẹ́bi níwájú rẹ̀,mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;ati gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ lójú rẹ̀. Ò máa dúró ti àwọn tí ó dúró tì ọ́,ò sì máa ṣe àṣepé fún àwọn tí ó pé; mímọ́ ni ọ́ sí àwọn tí ọkàn wọn mọ́,ṣugbọn àwọn alárèékérekè ni o fi ọgbọ́n tayọ. Nítorí tí o máa ń gba àwọn onírẹ̀lẹ̀ là,ṣugbọn o máa ń rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀. Nítorí ìwọ ni o mú kí àtùpà mi máa tàn,OLUWA, Ọlọrun mi ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn mi. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, mo lè run ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun,àní, pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun mi, mo lè fo odi ìlú. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ,ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Ní ti Ọlọrun, ọ̀nà rẹ̀ pé,pípé ni ọ̀rọ̀ OLUWA;òun sì ni ààbò fún gbogbo àwọn tí ó sá di í. Ta tún ni Ọlọrun, bíkòṣe OLUWA?Àbí, ta ni àpáta, àfi Ọlọrun wa? Ọlọrun tí ó gbé agbára wọ̀ mí,tí ó sì mú ọ̀nà mi pé. Ó fi eré sí mi lẹ́sẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín,ó sì fún mi ní ààbò ní ibi ìsásí. Ó kọ́ mi ní ogun jíjàtóbẹ́ẹ̀ tí mo fi lè fa ọrun idẹ. O ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ,ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó gbé mi ró,ìrànlọ́wọ́ rẹ sì ni ó sọ mí di ẹni ńlá. O la ọ̀nà tí ó gbòòrò fún mi,n kò sì fi ẹsẹ̀ rọ́. Mo lé àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ mi sì tẹ̀ wọ́n,n kò bojú wẹ̀yìn títí a fi pa wọ́n run. Mo ṣá wọn lọ́gbẹ́, wọn kò lè dìde,wọ́n ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ mi. O gbé agbára ogun wọ̀ mí;o sì mú àwọn tí ó dìde sí mi wólẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ mi. Ikú wé mọ́ mi bí okùn,ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi rírú omi. O mú kí àwọn ọ̀tá mi máa sá níwájú mi,mo sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run. Wọ́n kígbe pé, “Ẹ gbà wá o!”Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n,wọ́n ké pe OLUWA, ṣugbọn kò dá wọn lóhùn. Mo lọ̀ wọ́n lúbúlúbú bí eruku tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ,mo dà wọ́n nù bí ẹni da omi ẹrẹ̀ nù. O gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan,o fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè;àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò mọ̀ rí sì ń sìn mí. Bí wọ́n bá ti gbúròó mi ni wọ́n ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu;àwọn àjèjì ń fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba, wọ́n ń wá ojurere mi. Àyà pá àwọn àlejò,wọ́n sì fi ìbẹ̀rùbojo sá jáde kúrò ní ibi tí wọ́n sápamọ́ sí. OLUWA wà láàyè! Ẹni ìyìn ni àpáta mi!Ẹni àgbéga ni Ọlọrun ìgbàlà mi! Ọlọrun tí ó ń gbẹ̀san fún mi,tí ó sì ń tẹ orí àwọn eniyan ba fún mi; Ọlọrun tí ó gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;tí ó sì gbé mi ga ju àwọn abínú-ẹni lọ;ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ipá tí ó dìde sí mi. Nítorí náà ni èmi ó ṣe máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, OLUWA,èmi ó sì máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ. Isà òkú yí mi ká,tàkúté ikú sì dojú kọ mí. Ó fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀,ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ han ẹni àmì òróró rẹ̀,àní Dafidi ati ìrandíran rẹ̀ títí lae. Ninu ìpọ́njú mi mo ké pe OLUWA,Ọlọrun mi ni mo ké pè.Ó gbọ́ ohùn mi láti inú ilé mímọ́ rẹ̀,ó sì tẹ́tí sí igbe mi. Ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,ìpìlẹ̀ àwọn òkè mì jìgìjìgì;wọ́n wárìrì nítorí tí ó bínú. Èéfín ṣẹ́ jáde láti ihò imú rẹ̀,iná ajónirun yọ jáde láti ẹnu rẹ̀;ẹ̀yinná sì ń jò bùlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Ó dẹ ojú ọ̀run sílẹ̀, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá,ìkùukùu tó ṣókùnkùn biribiri sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ògo Ọlọrun ninu àwọn ohun tí Ó dá. Ojú ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọrun,òfuurufú sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n wuni ju wúrà lọ,àní ju ojúlówó wúrà lọ;wọ́n sì dùn ju oyin,àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ. Pẹlupẹlu àwọn ni wọ́n ń ki èmi iranṣẹ rẹ, nílọ̀,èrè pupọ sì ń bẹ ninu pípa wọ́n mọ́. Ṣugbọn ta ni lè mọ àṣìṣe ara rẹ̀?Wẹ̀ mí mọ́ ninu àṣìṣe àìmọ̀ mi. Pa èmi iranṣẹ rẹ mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀-ọ́n-mọ̀-dá;má jẹ́ kí wọ́n jọba lórí mi.Nígbà náà ni ara mi yóo mọ́,n kò sì ní jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ati àṣàrò ọkàn mijẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,OLUWA ibi ààbò mi ati olùràpadà mi. Ọjọ́ dé ọjọ́ ń sọ ọ́ ní àsọgbàòru dé òru sì ń fi ìmọ̀ rẹ̀ hàn. Wọn kò fọ èdè kankan, wọn kò sì sọ ọ̀rọ̀;bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ohùn wọn; sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já,ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé.Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run, tí ó ń yọ jáde bí ọkọ iyawo tí ń jáde láti inú yàrá rẹ̀,ati bí akọni tí ara ń wá láti fi tayọ̀tayọ̀ sáré ìje. Láti apá kan ojú ọ̀run ni ó ti ń yọ wá,a máa yípo gbogbo ojú ọ̀run dé apá keji;kò sì sí ohun tí ó bọ́ lọ́wọ́ ooru rẹ̀. Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí;àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n. Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀,àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú. Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae,ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn. Àyànfẹ́ Ọlọrun. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bínú fùfùtí àwọn eniyan ń gbìmọ̀ asán? Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ kọ́gbọ́n;ẹ̀yin onídàájọ́ ayé, ẹ gba ìkìlọ̀. Ẹ fi ìbẹ̀rù sin OLUWA,ẹ yọ̀ pẹlu ìwárìrì. Ẹ júbà ọmọ náà, kí ó má baà bínú,kí ó má baà pa yín run lójijì;nítorí a máa yára bínú.Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀,wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀. Wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á fa ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dè wá jákí á sì yọ ara wa kúrò lóko ẹrú wọn.” Ẹni tí ó gúnwà lọ́run ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín;OLUWA sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Lẹ́yìn náà, yóo sọ̀rọ̀ sí wọn ninu ibinu rẹ̀,yóo dẹ́rùbà wọ́n gidigidi ninu ìrúnú rẹ̀, Yóo wí pé, “Mo ti fi ọba mi jẹ,ní Sioni, lórí òkè mímọ́ mi.” N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba;Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi,lónìí ni mo bí ọ. Bèèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fún ọ ní àwọn orílẹ̀-èdè,gbogbo ayé yóo sì di tìrẹ. Ìwọ óo fi ọ̀pá irin fọ́ wọn,o óo sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.” Adura Ìṣẹ́gun. OLUWA óo dá ọ lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú,orúkọ Ọlọrun Jakọbu óo dáàbò bò ọ́. Yóo rán olùrànlọ́wọ́ sí ọ láti ilé mímọ́ rẹ̀ wá,yóo sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá. Yóo ranti gbogbo ẹbọ ọrẹ rẹ,yóo sì gba ẹbọ sísun rẹ. Yóo fún ọ ní ohun tí o fẹ́ ninu ọkàn rẹ,yóo sì mú gbogbo èrò rẹ ṣẹ. Ìhó ayọ̀ ni a óo hó nígbà tí o bá ṣẹgun,ní orúkọ Ọlọrun wa ni a óo sì fi ọ̀págun wa sọlẹ̀;OLUWA yóo dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ. Mo wá mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo ran ẹni àmì òróró rẹ̀ lọ́wọ́;OLUWA yóo dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wáyóo sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fún un ní ìṣẹ́gun ńlá. Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun,àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin,ṣugbọn ní tiwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa. Àwọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú,ṣugbọn àwa óo dìde, a óo sì dúró ṣinṣin. Fún ọba ní ìṣẹ́gun, OLUWA;kí o sì dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń ké pè ọ́. Orin Ìṣẹ́gun. Ọba ń yọ̀ nítorí agbára rẹ, OLUWA;inú rẹ̀ ń dùn lọpọlọpọ nítorí ríràn tí o ràn án lọ́wọ́! O óo pa àwọn ọmọ wọn run lórí ilẹ̀ ayé,o óo sì run ìran wọn láàrin àwọn eniyan. Bí wọn bá gbèrò ibi sí ọ,tí wọ́n sì pète ìkà, wọn kò ní lè ṣe é. Nítorí pé o óo lé wọn sá;nígbà tí o bá fi ọfà rẹ sun ojú wọn. A gbé ọ ga, nítorí agbára rẹ, OLUWA!A óo máa kọrin, a óo sì máa yin agbára rẹ. O ti fún un ní ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́,o kò sì fi ohun tí ó ń tọrọ dù ú. O gbé ibukun dáradára pàdé rẹ̀;o fi adé ojúlówó wúrà dé e lórí. Ó bèèrè ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ rẹ; o fi fún un,àní, ọjọ́ gbọọrọ títí ayé. Òkìkí rẹ̀ pọ̀ nítorí pé o ràn án lọ́wọ́;o sì fi iyì ati ọlá ńlá jíǹkí rẹ̀. Nítòótọ́ o sọ ọ́ di ẹni ibukun títí lae;o sì mú kí inú rẹ̀ dùn nítorí pé o wà pẹlu rẹ̀. Nítorí pé ọba gbẹ́kẹ̀lé OLUWA;a kò ní ṣí i ní ipò pada,nítorí ìfẹ́ Ọ̀gá Ògo tí kì í yẹ̀. Ọwọ́ rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ;ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn tí ó kórìíra rẹ. O óo jó wọn run bí iná ìléru, nígbà tí o bá yọ sí wọn.OLUWA yóo gbé wọn mì ninu ibinu rẹ̀;iná yóo sì jó wọn ní àjórun. Igbe Ìrora ati Orin Ìyìn. Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀,tí o fi jìnnà sí mi, tí o kò gbọ́ igbe mi,kí o sì ràn mí lọ́wọ́? Ìwọ ni wọ́n bí mi lé lọ́wọ́;ìwọ ni Ọlọrun miláti ìgbà tí ìyá mi ti bí mi. Má jìnnà sí mi,nítorí pé ìyọnu wà nítòsí,kò sì sí ẹni tí yóo ràn mí lọ́wọ́. Àwọn ọ̀tá yí mi ká bí akọ mààlúù,wọ́n yí mi ká bí akọ mààlúù Baṣani tó lágbára. Wọ́n ya ẹnu wọn sí mi bí kinniun,bí kinniun tí ń dọdẹ kiri tí ń bú ramúramù. Agbára mi ti lọ, ó ti ṣàn dànù bí omi,gbogbo egungun mi ti yẹ̀ lóríkèéríkèé;ọkàn mi dàbí ìda, ó ti yọ́. Okun inú mi ti gbẹ bí àpáàdì,ahọ́n mi sì ti lẹ̀ mọ́ mi lẹ́nu;o ti fi mí sílẹ̀ sinu eruku isà òkú. Àwọn eniyan burúkú yí mi ká bí ajá;àwọn aṣebi dòòyì ká mi;wọ́n fa ọwọ́ ati ẹsẹ̀ mi ya. Mo lè ka gbogbo egungun miwọ́n tẹjúmọ́ mi; wọ́n ń fojú burúkú wò mí. Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn,wọ́n ṣẹ́ gègé nítorí ẹ̀wù mi. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, má jìnnà sí mi!Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi, ṣe gírí láti ràn mí lọ́wọ́! Ọlọrun mi, mo kígbe pè ọ́ lọ́sàn-án,ṣugbọn o ò dáhùn;mo kígbe lóru, n ò sì dákẹ́. Gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ idà,gbà mí lọ́wọ́ àwọn ajá! Já mi gbà kúrò lẹ́nu kinniun nnìgbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwo ẹhànnà mààlúù! N óo ròyìn orúkọ rẹ fún àwọn ará mi;láàrin àwùjọ àwọn eniyan ni n óo sì ti máa yìn ọ́: Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ máa yìn ín!Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ fi ògo fún un,ẹ dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ níwájú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Nítorí pé kò fi ojú pa ìjìyà àwọn tí à ń jẹ níyà rẹ́;kò sì ṣá wọn tì,bẹ́ẹ̀ ni kò fi ojú pamọ́ fún wọn,ṣugbọn ó gbọ́ nígbà tí wọ́n ké pè é. Ìwọ ni n óo máa yìn láàrin àwùjọ àwọn eniyan;n óo san ẹ̀jẹ́ mi láàrin àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA. Àwọn tí ojú ń pọ́n yóo jẹ àjẹyó;àwọn tí ń wá OLUWA yóo yìn ín!Kí ẹ̀mí wọn ó gùn! Gbogbo ayé ni yóo ranti OLUWAwọn yóo sì pada sọ́dọ̀ rẹ̀;gbogbo ẹ̀yà àwọn orílẹ̀-èdèni yóo sì júbà níwájú rẹ̀. Nítorí OLUWA ló ni ìjọba,òun ní ń jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè. Gbogbo àwọn agbéraga láyé ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀;gbogbo ẹni tí yóo fi ilẹ̀ bora bí aṣọni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀,àní, gbogbo àwọn tí kò lè dá sọ ara wọn di alààyè. Sibẹ Ẹni Mímọ́ ni ọ́,o gúnwà, Israẹli sì ń yìn ọ́. Ìran tí ń bọ̀ yóo máa sìn ín;àwọn eniyan yóo máa sọ̀rọ̀ OLUWA fún àwọn ìran tí ń bọ̀. Wọn óo máa kéde ìgbàlà rẹ̀ fún àwọn ọmọ tí a kò tíì bí,pé, “OLUWA ló ṣe é.” Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀lé;wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ, o sì gbà wọ́n. Wọ́n kígbe pè ọ́, o sì gbà wọ́n;ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, ojú kò sì tì wọ́n. Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan;ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà. Gbogbo àwọn tí ó rí mi ní ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́;wọ́n ń yọ ṣùtì sí mi;wọ́n sì ń mi orí pé, “Ṣebí OLUWA ni ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé lọ́wọ́;kí OLUWA ọ̀hún yọ ọ́, kí ó sì gbà á là,ṣebí inú rẹ̀ dùn sí i!” Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi;ìwọ ni o sì mú mi wà láìséwu nígbà tí mo wà ní ọmọ ọmú. OLUWA ni Olùṣọ́ Mi. OLUWA ni Olùṣọ́-aguntan mi,n kò ní ṣe àìní ohunkohun. Ó mú mi dùbúlẹ̀ ninu pápá koríko tútù,ó mú mi lọ sí ibi tí omi ti dákẹ́ rọ́rọ́; ó sọ agbára mi dọ̀tun.Ó tọ́ mi sí ọ̀nà òdodonítorí orúkọ rẹ̀. Àní, bí mo tilẹ̀ ń rìn ninu òkùnkùn létí bèbè ikú, n kò ní bẹ̀rù ibi kankan;nítorí tí o wà pẹlu mi;ọ̀gọ rẹ ati ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀. O gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú mi,níṣojú àwọn ọ̀tá mi;o da òróró sí mi lórí;o sì bu ife mi kún ní àkúnwọ́sílẹ̀. Dájúdájú, ire ati àánú yóo máa tẹ̀lé mi kiri,ní gbogbo ọjọ́ ayé mi;èmi óo sì máa gbé inú ilé OLUWA laelae. Ọba Atóbijù. OLUWA ló ni ilẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó wàninu rẹ̀,òun ló ni ayé, ati gbogbo àwọn tíń gbé inú rẹ̀; Ta ni Ọba ògo yìí?OLUWA àwọn ọmọ ogun,òun ni Ọba ògo náà. nítorí pé òun ló fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí òkun,ó sì gbé e kalẹ̀ lórí ìṣàn omi. Ta ló lè gun orí òkè OLUWA lọ?Ta ló sì lè dúró ninu ibi mímọ́ rẹ̀? Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí inú rẹ̀ sì funfun,tí kò gbẹ́kẹ̀lé oriṣa lásánlàsàn,tí kò sì búra èké. Òun ni yóo rí ibukun gbà lọ́dọ̀ OLUWA,tí yóo sì rí ìdáláre gbà lọ́wọ́ Ọlọrun, Olùgbàlà rẹ̀. Irú wọn ni àwọn tí ń wá OLUWA,àní àwọn tí ń wá ojurere Ọlọrun Jakọbu. Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,kí Ọba ògo lè wọlé. Ta ni Ọba ògo yìí?OLUWA tí ó ní ipá tí ó sì lágbára,OLUWA tí ó lágbára lógun. Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,kí Ọba ògo lè wọlé. Adura fún ìtọ́sọ́nà ati Ààbò. OLUWA, ìwọ ni mo gbé ojú ẹ̀bẹ̀ sókè sí. Gbogbo ọ̀nà OLUWA ni ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́,fún àwọn tí ń pa majẹmu ati òfin rẹ̀ mọ́. Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí,nítorí mo jẹ̀bi lọpọlọpọ. Ẹni tí ó bá bẹ̀rù OLUWAni OLUWA yóo kọ́ ní ọ̀nà tí yóo yàn. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀,àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo sì jogún ilẹ̀ náà. Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́,a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn wọ́n. OLUWA ni mò ń wò lójú nígbà gbogbo,nítorí òun ni yóo yọ ẹsẹ̀ mi kúrò ninu àwọ̀n. Kọjú sí mi kí o sì ṣàánú mi;nítorí n kò lẹ́nìkan, ojú sì ń pọ́n mi. Mú ìdààmú ọkàn mi kúrò;kí o sì yọ mí ninu gbogbo ìpọ́njú mi. Wo ìpọ́njú ati ìdààmú mi,kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Wo iye ọ̀tá tí èmi nìkan ní,ati irú ìkórìíra ìkà tí wọ́n kórìíra mi. Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé,má jẹ́ kí ojú ó tì mí;má jẹ́ kí ọ̀tá ó yọ̀ mí. Pa mí mọ́, kí o sì gbà mí;má jẹ́ kí ojú kí ó tì mí,nítorí ìwọ ni mo sá di. Nítorí pípé mi ati òdodo mi, pa mí mọ́,nítorí pé ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Ọlọrun, ra Israẹli pada,kúrò ninu gbogbo ìyọnu rẹ̀. OLUWA, má jẹ́ kí ojú ó ti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ;àwọn ọ̀dàlẹ̀ eniyan ni kí ojú ó tì. Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, OLUWA,kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ. Tọ́ mi sí ọ̀nà òtítọ́ rẹ, sì máa kọ́ mi,nítorí ìwọ ni Ọlọrun olùgbàlà mi;ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé ní ọjọ́ gbogbo. OLUWA, ranti àánú rẹ, ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,nítorí wọ́n ti wà ọjọ́ ti pẹ́. Má ranti ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti ṣẹ̀ ní ìgbà èwe mi,tabi ibi tí mo ti kọjá ààyè mi;ranti mi, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,ati nítorí oore rẹ. Olóore ati olódodo ni OLÚWA,nítorí náà ni ó ṣe ń fi ọ̀nà han àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. A máa tọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́,a sì máa kọ́ wọn ní ìlànà rẹ̀. Adura Ẹni Rere. Dá mi láre, OLUWA,nítorí ninu ìwà pípé ni mò ń rìn,mo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA láìṣiyèméjì. àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún iṣẹ́ ibi,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn ní tèmi, èmi ń rìn ninu ìwà pípé;rà mí pada, kí o sì ṣàánú mi. Mo dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;láwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan ni n óo máa yin OLUWA. Yẹ̀ mí wò, OLUWA, dán mi wò;yẹ inú mi wò, sì ṣe akiyesi ọkàn mi. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni mo tẹjúmọ́,mo sì ń fi òtítọ́ bá ọ rìn. N kò jókòó ti àwọn èké,n kò sì gba ìmọ̀ràn àwọn ẹlẹ́tàn; mo kórìíra wíwà pẹlu àwọn aṣebi,n kò sì jẹ́ bá àwọn eniyan burúkú da nǹkan pọ̀. Ọwọ́ mi mọ́, n kò ní ẹ̀bi, OLUWA,mo sì ń jọ́sìn yí pẹpẹ rẹ ká. Mò ń kọ orin ọpẹ́ sókè,mo sì ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ. OLUWA, mo fẹ́ràn ilé rẹ, tí ò ń gbé,ati ibi tí ògo rẹ wà. Má pa mí run pẹlu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,má sì gba ẹ̀mí mi pẹlu ti àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìpànìyàn, Adura Ìyìn. OLUWA ni ìmọ́lẹ̀ ati ìgbàlà mi;ta ni n óo bẹ̀rù?OLUWA ni ààbò ẹ̀mí mi,ẹ̀rù ta ni yóo bà mí? Bí baba ati ìyá mi tilẹ̀ kọ̀ mí sílẹ̀,OLUWA yóo tẹ́wọ́gbà mí. Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLUWA,kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà títẹ́jú rẹ,nítorí àwọn ọ̀tá mi. Má fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́;nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde sí mi,ètè wọn sì kún fún ọ̀rọ̀ ìkà. Mo gbàgbọ́ pé n óo rí oore OLUWA gbàní ilẹ̀ alààyè. Dúró de OLUWA,ṣe bí akin, kí o sì mú ọkàn gírí,àní, dúró de OLUWA. Nígbà tí àwọn aṣebi bá ń gbógun bọ̀ wá bá mi,tí wọ́n fẹ́ pa mí,àwọn alátakò ati àwọn ọ̀tá mi,wọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú. Bí ogun tilẹ̀ dó tì míàyà mi kò ní já.Bí wọ́n tilẹ̀ gbé ogun wá bá mi,sibẹ, ọkàn mi kò ní mì. Ohun kan ni mo ti tọrọ lọ́dọ̀ OLUWA,òun ni n óo sì máa lépa:Kí n lè máa gbé inú ilé OLUWAní gbogbo ọjọ́ ayé mi,kí n lè máa wo ẹwà OLUWA,kí n sì máa fi tọkàntọkàn sìn ín ninu tẹmpili rẹ̀. Nítorí pé, nígbà tí ìpọ́njú bá dé,yóo fi mí pamọ́ sinu àgọ́ rẹ̀,lábẹ́ ààbò, ninu àgọ́ rẹ̀, ni yóo fi mí pamọ́ sí;yóo sì gbé mi sókè ka orí àpáta. Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gunlórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká;n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀,n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA. Gbọ́ OLUWA, nígbà tí mo bá ń kígbe pè ọ́;ṣàánú mi kí o sì dá mi lóhùn. Nígbà tí o wí pé, “Ẹ máa wá ojú mi.”Ọkàn mi dá ọ lóhùn pé, “Ojú rẹ ni n óo máa wá, OLUWA, má fi ojú pamọ́ fún mi!”Má fi ibinu lé èmi iranṣẹ rẹ kúrò,ìwọ tí o ti ń ràn mí lọ́wọ́,má ta mí nù, má sì ṣá mi tì,Ọlọrun ìgbàlà mi. Adura Ìrànlọ́wọ́. Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA,ìwọ ni ààbò mi, má di etí sí mi.Nítorí bí o bá dákẹ́ sí min óo dàbí àwọn òkú, tí wọ́n ti lọ sinu kòtò. Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi,bí mo ti ń kígbe sí ọ pé kí o ràn mí lọ́wọ́;tí mo gbé ọwọ́ mi sókèsí ìhà ilé mímọ́ rẹ. Má ṣe kó mi lọ pẹlu àwọn eniyan burúkú,pẹlu àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,àwọn tí ń bá àwọn aládùúgbò wọnsọ ọ̀rọ̀ alaafia,ṣugbọn tí ètekéte ń bẹ ninu ọkàn wọn. San án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn,àní gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ burúkú wọn;san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn,fún wọn ní èrè tí ó tọ́ sí wọn. Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ OLUWA sí,wọn kò sì bìkítà fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,OLUWA yóo sọ wọ́n di ilẹ̀,kò sì ní gbé wọn dìde mọ́. Ẹni ìyìn ni OLUWA!Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. OLUWA ni agbára ati asà mi,òun ni mo gbẹ́kẹ̀lé;ó ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀;mo sì fi orin ìyìn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. OLUWA ni agbára àwọn eniyan rẹ̀;òun ni ààbò ìgbàlà fún ẹni àmì òróró rẹ̀. Gba àwọn eniyan rẹ là, OLUWA,kí o sì bukun ilẹ̀ ìní rẹ.Jẹ́ olùṣọ́-aguntan wọn,kí o sì máa tọ́jú wọn títí lae. Agbára OLUWA ninu ìjì. Ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi ògo fún OLUWA,ẹ gbé agbára rẹ̀ lárugẹ. OLUWA jókòó, ó gúnwà lórí ìkún omi;OLUWA jókòó, ó gúnwà bí ọba títí lae. OLUWA yóo fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára;OLUWA yóo fún wọn ní ibukun alaafia. Ẹ fún OLUWA ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀,ẹ máa sin OLUWA ninu ẹwà mímọ́ rẹ̀. À ń gbọ́ ohùn OLUWA lójú omi òkun,Ọlọrun ológo ń sán ààrá,Ọlọrun ń sán ààrá lójú alagbalúgbú omi. Ohùn OLUWA lágbára,ohùn OLUWA kún fún ọlá ńlá. Ohùn OLUWA ń fọ́ igi kedari,OLUWA ń fọ́ igi kedari ti Lẹbanoni. Ó ń mú kí òkè Lẹbanoni ta pọ́núnpọ́nún bí ọmọ mààlúù,ó sì mú kí òkè Sirioni máa fò bí akọ ọmọ mààlúù-igbó. Ohùn OLUWA ń yọ iná lálá. Ohùn OLUWA ń mi aṣálẹ̀;OLUWA ń mi aṣálẹ̀ Kadeṣi. Ohùn OLUWA a máa mú abo àgbọ̀nrín bí,a máa wọ́ ewé lára igi oko;gbogbo eniyan ń kígbe ògo rẹ̀ ninu Tẹmpili rẹ̀. Adura ìrànlọ́wọ́ lówùúrọ̀ . OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ!Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi! Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé,Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀! Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi,ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà. Mo ké pe OLUWA,ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí,nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró. Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀tá tó yí mi kákò le bà mí lẹ́rù. Dìde, OLUWA, gbà mí, Ọlọrun mi!Nítorí ìwọ ni o lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi bolẹ̀,tí o sì ṣẹgun àwọn eniyan burúkú. OLUWA níí gbani,kí ibukun rẹ̀ kí ó wà lórí àwọn eniyan rẹ̀. Adura Ọpẹ́. N óo yìn ọ́, OLUWA,nítorí pé o ti yọ mí jáde;o kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí. Gbọ́ OLUWA, kí o sì ṣàánú mi,OLUWA, ràn mí lọ́wọ́. O ti bá mi sọ ọ̀fọ̀ mi di ijó,o ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò lára mi,o sì ti dì mí ní àmùrè ayọ̀, kí ọkàn mi lè máa yìn ọ́ láìdákẹ́.OLUWA Ọlọrun mi, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ títí lae. OLUWA, Ọlọrun mi, mo ké pè ọ́,o sì wò mí sàn. OLUWA, o ti yọ mí kúrò ninu isà òkúo sọ mí di ààyè láàrin àwọn tíwọ́n ti wọ inú kòtò. Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA, ẹ̀yin olùfọkànsìn rẹ̀,kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀. Nítorí pé fún ìgbà díẹ̀ ni ibinu rẹ̀,ṣugbọn títí ayé ni ojurere rẹ̀;eniyan lè máa sọkún títí di alẹ́,ṣugbọn ayọ̀ ń bọ̀ fún un lówùúrọ̀. Nígbà tí ara rọ̀ mí,mo wí ninu ọkàn mi pé,kò sí ohun tí ó lè mì mí laelae. Nípa ojurere rẹ, OLUWA,o ti fi ìdí mi múlẹ̀ bí òkè ńlá;ṣugbọn nígbà tí o fi ojú pamọ́ fún mi,ìdààmú dé bá mi. Ìwọ ni mò ń ké pè, OLUWA,OLUWA, ìwọ ni mò ń bẹ̀. Anfaani wo ló wà ninu pé kí n kú?Èrè wo ló wà ninu pé kí n wọ inú kòtò?Ṣé erùpẹ̀ lè yìn ọ́?Ṣé ó lè sọ nípa òdodo rẹ? Adura Igbẹkẹle Ọlọrun. OLUWA, ìwọ ni mo sá di,má jẹ́ kí ojú tì mí lae;gbà mí, nítorí olóòótọ́ ni ọ́. Nítorí pé ìbànújẹ́ ni mo fi ń lo ayé mi;ìmí ẹ̀dùn ni mo sì fi ń lo ọdún kan dé ekeji.Ìpọ́njú ti gba agbára mi;gbogbo egungun mi sì ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Ẹni ẹ̀gàn ni mí láàrin gbogbo àwọn ọ̀tá mi,àwòsọkún ni mí fún àwọn aládùúgbò.Mo di àkòtagìrì fún àwọn ojúlùmọ̀ mi,àwọn tí ó rí mi lóde sì ń sá fún mi. Mo di ẹni ìgbàgbé bí ẹni tí ó ti kú;mo dàbí àkúfọ́ ìkòkò. Mò ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,bí wọ́n ti ń gbìmọ̀ pọ̀ nípa mi,tí wọ́n sì ń pète ati pa mí;wọ́n ń ṣẹ̀rù bà mí lọ́tùn-ún lósì. Ṣugbọn, mo gbẹ́kẹ̀lé ọ, OLUWA,Mo ní, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.” Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi,ati lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi. Jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ rí ojurere rẹ,gbà mí là, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Má jẹ́ kí ojú tì mí, OLUWA,nítorí ìwọ ni mò ń ké pè.Jẹ́ kí ojú ti àwọn eniyan burúkú;jẹ́ kí ẹnu wọn wọ wòwò títí wọ ibojì. Jẹ́ kí àwọn òpùrọ́ yadi,àní àwọn tí ń fi ìgbéraga ati ẹ̀gàn sọ̀rọ̀ àìdára nípa olódodo. Háà! Ohun rere mà pọ̀ lọ́wọ́ rẹ otí o ti sọ lọ́jọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,tí o sì ti pèsè ní ìṣojú àwọn ọmọ eniyan,fún àwọn tí ó sá di ọ́. Dẹ etí sí mi, yára gbà mí.Jẹ́ àpáta ààbò fún mi;àní ilé ààbò tó lágbára láti gbà mí là. O fi ìyẹ́ apá rẹ ṣíji bò wọ́n;o pa wọ́n mọ́ kúrò ninu rìkíṣí àwọn eniyan;o sì pa wọ́n mọ́ lábẹ́ ààbò rẹ,kúrò lọ́wọ́ ẹnu àwọn ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́. Ẹni ìyìn ni OLUWA, nítorí pé, lọ́nà ìyanu,ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí,nígbà tí ilẹ̀ ká mi mọ́. Ẹ̀rù bà mí, mo sì sọ pé,“A lé mi jìnnà kúrò ní iwájú rẹ.”Ṣugbọn o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ minígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. Ẹ fẹ́ràn OLUWA, gbogbo ẹ̀yin olódodo,OLUWA a máa ṣọ́ àwọn olóòótọ́,a sì máa san àlékún ẹ̀san fún àwọn agbéraga. Ẹ múra gírí, kí ẹ sì mọ́kàn le,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ìwọ ni àpáta ati ilé ààbò mi;nítorí orúkọ rẹ, máa tọ́ mi kí o sì máa fọ̀nà hàn mí. Yọ mí kúrò ninu àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ dè mí,nítorí ìwọ ni ẹni ìsádi mi. Ìwọ ni mo fi ẹ̀mí mi lé lọ́wọ́,o ti rà mí pada, OLUWA, Ọlọrun, olóòótọ́. Mo kórìíra àwọn tí ń bọ oriṣa lásánlàsàn,ṣugbọn OLUWA ni èmi gbẹ́kẹ̀lé. N óo máa yọ̀, inú mi óo sì máa dùn,nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;nítorí pé o ti rí ìpọ́njú mi,o sì mọ ìṣòro mi. O ò fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́,o sì ti fi ẹsẹ̀ mi lé ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí pé mo wà ninu ìṣòro.Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì;àárẹ̀ sì mú ọkàn ati ara mi. Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí a dárí ìrékọjá rẹ̀ jì,tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ìrora pọ̀ fún àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ó yí àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ká. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA;ẹ fò fún ayọ̀, ẹ̀yin olódodo;kí ẹ sì hó fún ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn mímọ́. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí OLUWA kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn,tí ẹ̀tàn kò sì sí ninu ọkàn rẹ̀. Nígbà tí n kò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi,ó rẹ̀ mí wá láti inú,nítorí kíkérora tí mò ń kérora ní gbogbo ìgbà. Nítorí tọ̀sán-tòru ni o fi ń jẹ mí níyà;gbogbo agbára mi ló lọ háú,bí omi tíí gbẹ lákòókò ẹ̀ẹ̀rùn. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ;n kò sì fi àìdára mi pamọ́ fún ọ.Mo ní, “Èmi óo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Oluwa,”o sì dáríjì mí. Nítorí náà, kí gbogbo olódodo máa gbadura sí ọ;ní àkókò tí ìpọ́njú bá ń yí lura wọn bí ìṣàn omi ńlá,kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn. Ìwọ ni ibi ìsásí mi;o pa mí mọ́ kúrò ninu ìṣòro;o sì fi ìgbàlà yí mi ká. N óo kọ́ ọ, n óo sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tí o óo rìn;n óo máa gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn;n óo sì máa mójútó ọ. Má ṣe dàbí ẹṣin tabi ìbaaka,tí kò ni ọgbọ́n ninu,tí a gbọdọ̀ kó ìjánu sí lẹ́nukí ó tó lè gbọ́ ti oluwa rẹ̀. Orin Ìyìn. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo!Yíyin OLUWA ni ó yẹ ẹ̀yin olóòótọ́. OLUWA sọ ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè di asán;ó sì mú kí ètò àwọn eniyan já sófo. Ètò OLUWA wà títí lae,èrò ọkàn rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran. Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn,àní àwọn eniyan tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀! OLUWA bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run,ó rí gbogbo eniyan; láti orí ìtẹ́ rẹ̀ tí ó gúnwà sí,ó wo gbogbo aráyé. Òun ni ó dá ọkàn gbogbo wọn,tí ó sì ń mójútó gbogbo ìṣe wọn. Kì í ṣe pípọ̀ tí àwọn ọmọ ogun pọ̀ ní ń gba ọba là;kì í sì í ṣe ọ̀pọ̀ agbára níí gba jagunjagun là. Asán ni igbẹkẹle agbára ẹṣin ogun;kìí ṣe agbára tí ẹṣin ní, ló lè gbani là. Wò ó! OLUWA ń ṣọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àní àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, kí ó lè gba ọkàn wọn lọ́wọ́ ikú,kí ó sì mú wọn wà láàyè lákòókò ìyàn. Ẹ fi gòjé yin OLUWA,ẹ fi hapu olókùn mẹ́wàá kọ orin sí i. Ọkàn wa ní ìrètí lọ́dọ̀ OLUWA;òun ni olùrànlọ́wọ́ ati ààbò wa. A láyọ̀ ninu rẹ̀,nítorí pé a gbẹ́kẹ̀lé orúkọ mímọ́ rẹ̀. OLUWA, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà lórí wabí a ti gbẹ́kẹ̀lé ọ. Ẹ kọ orin titun sí i,ẹ fi ohun èlò ìkọrin olókùn dárà,kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀. Nítorí ọ̀rọ̀ OLUWA dúró ṣinṣin;òtítọ́ sì ni ó fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. OLUWA fẹ́ràn òdodo ati ẹ̀tọ́;ayé kún fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ọ̀rọ̀ ni OLUWA fi dá ojú ọ̀run,èémí ẹnu rẹ̀ ni ó sì fi dá oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀. Ó wọ́ gbogbo omi òkun jọ bí òkìtì;ó pa gbogbo omi inú àwọn ibú pọ̀ bí ẹni pé ó rọ ọ́ sinu àgbá ńlá. Kí gbogbo ayé bẹ̀rù OLUWA,kí gbogbo aráyé dúró níwájú rẹ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù! Nítorí pé OLUWA sọ̀rọ̀, ayé wà;ó pàṣẹ, ayé sì dúró. Ẹ yin Ọlọrun nítorí Oore Rẹ̀ . N óo máa yin OLUWA ní gbogbo ìgbà;ìyìn rẹ̀ yóo máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo. Àwọn ọmọ kinniun a máa ṣe aláìní,ebi a sì máa pa wọ́n;ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá ń wá OLUWAkò ní ṣe aláìní ohun rere kankan. Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ tẹ́tí sí mi,n óo kọ yín ní ìbẹ̀rù OLUWA. Ta ni ń fẹ́ ìyè ninu yín,tí ń fẹ́ ẹ̀mí gígùn,tí ó fẹ́ pẹ́ láyé? Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú,ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde. Ẹ yàgò fún ibi, rere ni kí ẹ máa ṣe;ẹ máa wá alaafia, kí ẹ sì máa lépa rẹ̀. OLUWA ń ṣọ́ àwọn olódodo,Ó sì ń dẹ etí sí igbe wọn. OLUWA fojú sí àwọn aṣebi lára,láti pa wọ́n rẹ́, kí á má sì ṣe ranti wọn mọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́,a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn. OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́,a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là. Ìpọ́njú olódodo a máa pọ̀;ṣugbọn OLUWA a máa kó o yọ ninu gbogbo wọn. OLUWA ni èmi óo máa fi yangàn;kí inú àwọn olùpọ́njú máa dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́. A máa pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́;kì í jẹ́ kí ọ̀kankan fọ́ ninu wọn. Ibi ni yóo pa eniyan burúkú;a óo sì dá àwọn tí ó kórìíra olódodo lẹ́bi. OLUWA ra ẹ̀mí àwọn iranṣẹ rẹ̀ pada;ẹnikẹ́ni tí ó bá sá di í kò ní jẹ̀bi. Ẹ bá mi gbé OLUWA ga,ẹ jẹ́ kí á jùmọ̀ gbé orúkọ rẹ̀ lékè! Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn,ó sì gbà mí lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ń bà mí lẹ́rù. Wọ́n gbójú sókè sí OLUWA, wọ́n láyọ̀; ojú kò sì tì wọ́n. Olùpọ́njú ké pe OLUWA, OLUWA gbọ́ ohùn rẹ̀,ó sì gbà á ninu gbogbo ìpọ́njú rẹ̀. Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká,a sì máa gbà wọ́n. Tọ́ ọ wò, kí o sì rí i pé rere ni OLUWA!Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá sá di í! Ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ̀yin eniyan mímọ́ rẹ̀,nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀! Adura ìrànlọ́wọ́. OLUWA, gbógun ti àwọn tí ń gbógun tì mí;gbé ìjà ko àwọn tí ń bá mi jà! N óo fi gbogbo ara wí pé,“OLUWA, ta ni ó dàbí rẹ?Ìwọ ni ò ń gba aláìlágbáralọ́wọ́ ẹni tí ó lágbáratí o sì ń gba aláìlágbára ati aláìnílọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ fi wọ́n ṣe ìjẹ.” Àwọn tí ń fi ìlara jẹ́rìí èké dìde sí mi;wọ́n ń bi mí léèrè ohun tí n kò mọ̀dí. Wọ́n fi ibi san oore fún mi,ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Bẹ́ẹ̀ sì ni, ní tèmi, nígbà tí wọn ń ṣàìsàn,aṣọ ọ̀fọ̀ ni mo wọ̀;mo fi ààwẹ̀ jẹ ara mi níyà;mo gbadura pẹlu ìtẹríba patapata, bí ẹni pé mò ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀rẹ́ mi, tabi arakunrin mi;mò ń lọ káàkiri, bí ẹni tí ń pohùnréré ẹkún ìyá rẹ̀,mo doríkodò, mo sì ń ṣọ̀fọ̀. Ṣugbọn nígbà tí èmi kọsẹ̀, wọ́n kó ara wọn jọ,wọ́n ń yọ̀,wọ́n kó tì mí;pàápàá jùlọ, àwọn àlejò tí n kò mọ̀ ríbẹ̀rẹ̀ sí purọ́ mọ́ mi léraléra. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pẹ̀gàn mi, wọ́n ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà;wọ́n sì ń wò mí bíi pé kí n kú. OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa wò mí níran?Yọ mí kúrò ninu ogun tí wọn gbé tì mí,gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn kinniun! Nígbà náà ni n óo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan;láàrin ọpọlọpọ eniyan ni n óo máa yìn ọ́. Má jẹ́ kí àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí yọ̀ mí,má sì jẹ́ kí àwọn tí ó kórìíra mi wò mí ní ìwò ẹ̀sín. Gbá asà ati apata mú,dìde, kí o sì ràn mí lọ́wọ́! Nítorí pé wọn kì í sọ̀rọ̀ alaafia sí àwọn tí wọn ń lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọnàfi kí wọ́n máa pète oríṣìíríṣìí ẹ̀tàn. Wọ́n la ẹnu, wọ́n ń pariwo lé mi lórí,wọ́n ń wí pé, “Ìn hín ìn, a rí ọ, ojú wa ló ṣe!” O ti rí i, OLUWA, má dákẹ́.OLUWA, má jìnnà sí mi. Paradà, OLUWA, jí gìrì sí ọ̀ràn mi,gbèjà mi, Ọlọrun mi, ati OLUWA mi! Dá mi láre, OLUWA, Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ;má sì jẹ́ kí wọ́n yọ̀ mí! Má jẹ́ kí wọ́n wí láàrin ara wọn pé,“Ìn hín ìn, ọwọ́ wa ba ohun tí a fẹ́!”Má jẹ́ kí wọn wí pé,“A rẹ́yìn ọ̀tá wa.” Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí ń yọ̀ pé ìpọ́njú dé bá mi;kí ìdààmú bá wọn;bá mi da aṣọ ìtìjú ati ẹ̀tẹ́ bo àwọn tí ń gbé àgbéré sí mi. Kí àwọn tí ń wá ìdáláre mimáa hó ìhó ayọ̀, kí inú wọn sì máa dùn,kí wọ́n máa wí títí ayé pé,“OLUWA tóbi,inú rẹ̀ dùn sí alaafia àwọn iranṣẹ rẹ̀.” Nígbà náà ni n óo máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ,n óo sì máa yìn ọ́ tọ̀sán-tòru. Fa ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojú kọ àwọn tí ń lépa mi!Ṣe ìlérí fún mi pé, ìwọ ni olùgbàlà mi. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi,kí wọn ó tẹ́!Jẹ́ kí àwọn tí ń gbìmọ̀ ibi sí mi dààmú,kí wọ́n sì sá pada sẹ́yìn! Kí wọ́n dàbí fùlùfúlù ninu afẹ́fẹ́,kí angẹli OLUWA máa lé wọn lọ! Jẹ́ kí ojú ọ̀nà wọn ṣóòkùn, kí ó sì máa yọ̀,kí angẹli OLUWA máa lépa wọn! Nítorí wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi láìnídìí,wọ́n sì gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí láìnídìí. Jẹ́ kí ìparun dé bá wọn lójijì,jẹ́ kí àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ dè mí mú wọn;jẹ́ kí wọ́n kó sinu rẹ̀, kí wọ́n sì parun! Nígbà náà ni n óo máa yọ̀ ninu OLUWA,n óo sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìgbàlà rẹ̀. Ìwà ìkà. Ẹ̀ṣẹ̀ ń gbin lọ́kàn eniyan burúkú,kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ninu èrò tirẹ̀. Túbọ̀ máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀han àwọn tí ó mọ̀ ọ́,sì máa fi òdodo rẹ han àwọn ọlọ́kàn mímọ́. Má jẹ́ kí àwọn agbéraga borí mi,má sì jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú lé mi kúrò. Ẹ wo àwọn aṣebi níbi tí wọ́n ṣubú sí;wọ́n dà wólẹ̀, wọn kò sì le dìde. Nítorí pé lọ́kàn rẹ̀ a máa pọ́n ara rẹ̀,pé kò sí ẹni tí ó lè rí ẹ̀ṣẹ̀ òun,ká tó wá sọ pé yóo dá òun lẹ́bi. Ọ̀rọ̀ ìkà ati ẹ̀tàn ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.Ó ti dáwọ́ ire ṣíṣe dúró;kò sì hu ìwà ọlọ́gbọ́n mọ́. A máa pète ìkà lórí ibùsùn rẹ̀;a máa rin ọ̀nà tí kò tọ́;kò sì kórìíra ibi. OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga kan ọ̀run;òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Òtítọ́ rẹ dàbí òkè ńlá;ìdájọ́ rẹ sì jìn bí ibú omi.OLUWA, àtènìyàn, àtẹranko ni ò ń gbàlà. Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ níye lórí pupọ, Ọlọrun!Àwọn ọmọ eniyan a máa sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ. Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó ní ilé rẹ;nǹkan mímu tí ń ṣàn bí odò,ni o sì ń fún wọn mu. Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà;ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀. Ìgbẹ̀yìn Àwọn Eniyan Burúkú. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú;má sì jowú àwọn aṣebi; Ẹ fún eniyan burúkú ní ìgbà díẹ̀ sí i, yóo pòórá;ẹ̀ báà wá a títí ní ààyè rẹ̀, kò ní sí níbẹ̀. Ṣugbọn àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóo jogún ilẹ̀ náà:wọn óo máa gbádùn ara wọn;wọn óo sì ní alaafia lọpọlọpọ. Eniyan burúkú dìtẹ̀ mọ́ olódodo;ó sì ń wò ó bíi kíkú bíi yíyè. Ṣugbọn OLUWA ń fi eniyan burúkú rẹ́rìn-ín,nítorí ó mọ̀ pé ọjọ́ ìparun rẹ̀ ń bọ̀. Àwọn eniyan burúkú fa idà yọ, wọ́n sì kẹ́ ọfà wọnláti gba ẹ̀mí talaka ati aláìní,láti pa àwọn tí ń rìn lọ́nà ẹ̀tọ́. Ṣugbọn idà wọn ni o óo fi pa wọ́n,ọrun wọn yóo sì dá. Nǹkan díẹ̀ tí olódodo nídára ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú. Nítorí OLUWA yóo ṣẹ́ apá eniyan burúkú,ṣugbọn yóo gbé olódodo ró. OLUWA a máa tọ́jú àwọn aláìlẹ́bi;ilẹ̀ ìní wọn yóo jẹ́ tiwọn títí lae. Ojú kò ní tì wọ́n nígbà tí àjálù bá dé;bí ìyàn tilẹ̀ mú, wọn óo jẹ, wọn óo yó. nítorí pé kíákíá ni wọn yóo gbẹ bí i koríko;wọn óo sì rọ bí ewé. Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé;àwọn ọ̀tá OLUWA yóo pòórá bí ẹwà ewékowọn óo parẹ́ bí èéfín tí í parẹ́. Bí eniyan burúkú bá yá owó, kò ní san;ṣugbọn ẹni rere ní ojú àánú, ó sì lawọ́. Nítorí pé àwọn tí Ọlọrun bá bukun ni yóo jogún ilẹ̀ náà,ṣugbọn àwọn tí ó bá fi gégùn-ún yóo parun. OLUWA níí darí ìgbésẹ̀ ẹni;a sì máa fi ẹsẹ̀ ẹni tí inú rẹ̀ bá dùn sí múlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ ṣubú, kò ní lulẹ̀ lógèdèǹgbé,nítorí OLUWA yóo gbé e ró. Mo ti jẹ́ ọmọde rí; mo sì ti dàgbà:n kò tíì ri kí á kọ olódodo sílẹ̀,tabi kí ọmọ rẹ̀ máa tọrọ jẹ. Olódodo ní ojú àánú, a sì máa yáni ní nǹkan,ayọ̀ ń bẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ yẹra fún ibi; ẹ sì máa ṣe rere;kí ẹ lè wà ní ààyè yín títí lae. Nítorí OLUWA fẹ́ràn ẹ̀tọ́;kò ní kọ àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sílẹ̀.Yóo máa ṣọ́ wọn títí lae,ṣugbọn a óo pa àwọn ọmọ eniyan burúkú run. Àwọn ẹni rere ni yóo jogún ilẹ̀ náà;wọn óo sì máa gbé orí rẹ̀ títí lae. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere.Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa jáde lẹ́nu ẹni rere,a sì máa sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́. Òfin Ọlọrun rẹ̀ wà ní ọkàn rẹ̀;ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í yà kúrò níbẹ̀. Eniyan burúkú ń ṣọ́ olódodo,ó ń wá ọ̀nà ati pa á. OLUWA kò ní fi olódodo lé e lọ́wọ́,tabi kí ó jẹ́ kí á dá olódodo lẹ́bi ní ilé ẹjọ́. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, sì máa tọ ọ̀nà rẹ̀,yóo gbé ọ ga, kí o lè jogún ilẹ̀ náà;nígbà tí a bá pa àwọn eniyan burúkú run, o óo fojú rẹ rí i. Mo ti rí eniyan burúkú tí ń halẹ̀ mọ́ni,tí ó ga bí igi kedari ti Lẹbanoni. Ṣugbọn nígbà tí mo tún gba ibẹ̀ kọjá,mo wò ó, kò sí níbẹ̀ mọ́;mo wá a, ṣugbọn n kò rí i. Ṣe akiyesi ẹni pípé;sì wo olódodo dáradára,nítorí pé ìgbẹ̀yìn ẹni tí ń wá alaafia yóo dára. Ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo parun patapata,a óo sì run ọmọ àwọn eniyan burúkú. Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìgbàlà àwọn olódodo ti ń wá;òun ni alátìlẹ́yìn wọn ní àkókò ìṣòro. Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA;yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́. OLUWA a máa ràn wọ́n lọ́wọ́, a sì máa gbà wọ́n;a máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,a sì máa gbà wọ́n là,nítorí pé òun ni wọ́n sá di. Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́;gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ. Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀;ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan. Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e.Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún;tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é. Yẹra fún ibinu; sì yàgò fún ìrúnú.Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná; ibi ni àyọrísí rẹ̀. Nítorí pé a óo pa àwọn eniyan burúkú run;ṣugbọn àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWAni yóo jogún ilẹ̀ náà. Adura Ẹni tí Ìyà ń Jẹ. OLUWA, má fi ibinu bá mi wí!Má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà! Àyà mi ń lù pì pì pì, ó rẹ̀ mí láti inú wá;ojú mi sì ti di bàìbàì. Àwọn ọ̀rẹ́ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi takété sí mi nítorí àrùn mi,àwọn ẹbí mi sì dúró lókèèrè réré. Àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí,àwọn tí ń wá ìpalára mi ń sọ̀rọ̀ ìparun mi,wọ́n sì ń pète àrékérekè tọ̀sán-tòru. Ṣugbọn mo ṣe bí adití, n kò gbọ́,mo dàbí odi tí kò le sọ̀rọ̀. Àní, mo dàbí ẹni tí kò gbọ́rọ̀,tí kò sì ní àwíjàre kan lẹ́nu. Ṣugbọn, OLUWA, ìwọ ni mò ń dúró dè;OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni o óo dá mi lóhùn. Nítorí tí mò ń gbadura pé,kí àwọn tí ń pẹ̀gàn mi má yọ̀ mínígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yẹ̀. Nítorí pé mo ti fẹ́rẹ̀ ṣubú,mo sì wà ninu ìrora nígbà gbogbo. Mo jẹ́wọ́ àṣìṣe mi,mo sì káàánú fún ẹ̀ṣẹ̀ mi. Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí lágbára,àwọn tí ó kórìíra mi láìtọ́ sì pọ̀. Nítorí pé ọfà rẹ ti wọ̀ mí lára,ọwọ́ rẹ sì ti bà mí. Àwọn tí ń fi ibi san oore fún mi ní ń gbógun tì mí,nítorí pé rere ni mò ń ṣe. OLUWA, má kọ̀ mí sílẹ̀,Ọlọrun mi, má jìnnà sí mi. Yára wá ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, ìgbàlà mi. Kò sí ibìkan tí ó gbádùn ní gbogbo ara minítorí ibinu rẹ;kò sì sí alaafia ninu gbogbo egungun mi,nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi. Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti bò mí lórí mọ́lẹ̀;ó rìn mí mọ́lẹ̀ bí ẹrù ńlátí ó wúwo jù fún mi. Ọgbẹ́ mi ń kẹ̀, ó sì ń rùn,nítorí ìwà òmùgọ̀ mi, Ìbànújẹ́ dorí mi kodò patapata,mo sì ń ṣọ̀fọ̀ kiri tọ̀sán-tòru. Gbogbo ẹ̀gbẹ́ mi ń gbóná fòò,kò sí ibìkan tí ó gbádùn lára mi. Àárẹ̀ mú mi patapata, gbogbo ara sì wó mi;mò ń kérora nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi. OLUWA, gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi ni o mọ̀,ìmí ẹ̀dùn mi kò sì pamọ́ fún ọ. Ìráhùn Ẹni tí Ìyà ń Jẹ. Mo ní, “Èmi óo máa ṣọ́ra,kí n má baà fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀;n óo kó ẹnu mi ní ìjánu,níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan burúkú bá wà nítòsí.” Dáwọ́ ẹgba rẹ dúró lára mi,mo ti fẹ́rẹ̀ kú nítorí ìyà tí o fi ń jẹ mí. Nígbà tí o bá jẹ eniyan níyàpẹlu ìbáwí nítorí ẹ̀ṣẹ̀,ìwọ á ba ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún un jẹ́ bíi kòkòrò aṣọ.Dájúdájú, afẹ́fẹ́ lásán ni eniyan. “OLUWA, gbọ́ adura mi,tẹ́tí sí igbe mi,má dágunlá sí ẹkún mi,nítorí pé àlejò rẹ, tí ń rékọjá lọ ni mo jẹ́;àjèjì sì ni mí, bíi gbogbo àwọn baba mi. Mú ojú ìbáwí kúrò lára mi,kí inú mi lè dùn kí n tó kọjá lọ;àní, kí n tó ṣe aláìsí.” Mo dákẹ́, n ò sọ nǹkankan;n ò tilẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ rere pàápàá;sibẹ ìpọ́njú mi ń pọ̀ sí i ìdààmú dé bá ọkàn mi.Bí mo ti ń ronú, ọkàn mi dàrú;mo bá sọ̀rọ̀ jáde, mo ní: “OLUWA, jẹ́ kí n mọ òpin ayé mi,ati ìwọ̀nba ọjọ́ ayé mi,kí n lè mọ̀ pé ayé mi ń sáré kọjá lọ.” Wò ó, o ti ṣe ọjọ́ mi ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ mélòó kan,ọjọ́ ayé mi kò sì tó nǹkankan ní ojú rẹ;dájúdájú, ọmọ eniyan dàbí afẹ́fẹ́ lásán. Dájúdájú, eniyan ń káàkiri bí òjìji,asán sì ni gbogbo làálàá rẹ̀;eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ ṣá,láìmọ ẹni tí yóo kó o lọ. Wàyí ò, OLUWA, kí ló kù tí mo gbójú lé?Ìwọ ni mo fẹ̀yìn tì. Gbà mí ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá mi;má sọ mí di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn òmùgọ̀. Mo dákẹ́, n kò ya ẹnu mi;nítorí pé ìwọ ni o ṣe é. Igbẹkẹle OLUWA. Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,Ọlọrun mi olùdániláre.Ìwọ ni o yọ mí nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú,ṣàánú mi, kí o sì gbọ́ adura mi. Ẹ̀yin ọmọ eniyan, yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo máa fi ojú ọlá mi gbolẹ̀,tí ẹ óo máa fẹ́ràn ọ̀rọ̀ asán, tí ẹ óo sì máa wá irọ́ kiri? Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ti ya olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀,OLUWA yóo gbọ́ nígbà tí mo bá pè é. Bí ó ti wù kí ẹ bínú tó, ẹ má dẹ́ṣẹ̀;ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀ lórí ibùsùn yín,kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Ẹ rú ẹbọ òdodo,kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń bèèrè pé “Ta ni yóo ṣe wá ní oore?”OLUWA, tan ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sí wa lára. Ìwọ ti fi ayọ̀ kún ọkàn miju ayọ̀ àwọn tí ó rí ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini nígbà ìkórè. N óo dùbúlẹ̀, n óo sì sùn ní alaafia,nítorí ìwọ OLUWA nìkan ni o mú mi wà láìléwu. Orin ìyìn. Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA,ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi. Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́.Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ;n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,ninu àwùjọ ńlá. Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA,sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́. Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká,ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí,tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran.Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,ọkàn mi ti dàrú. OLUWA, dákun gbà mi;yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́. Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́gba ẹ̀mí mi,kí ìdàrúdàpọ̀ bá gbogbo wọn patapata,jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,kí wọ́n sì tẹ́. Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n,kí wọ́n sì gba èrè ìtìjú,àní, àwọn tí ń ṣe jàgínní mi. Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀,kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ;kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹmáa wí nígbà gbogbo pé, “OLUWA tóbi!” Ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí;ṣugbọn Oluwa kò gbàgbé mi.Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ati olùgbàlà mi,má pẹ́, Ọlọrun mi. Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun,láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀;ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta,ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀. Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu,àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa.Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà,tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA,tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn,àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa. OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa,o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá.Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ;bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe,kí n máa ròyìn wọn,wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ. O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ,ṣugbọn o là mí ní etí;o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé;a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé: mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi;mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.” Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá.Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́,gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀. Adura Ẹni tí ń Ṣàìsàn. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń ro ti àwọn aláìní:OLUWA yóo gbà á ní ọjọ́ ìpọ́njú. Ṣugbọn, OLUWA, ṣàánú mi;gbé mi dìde, kí n lè san ẹ̀san fún un. Kí n lè mọ̀ pé o fẹ́ràn mi,nígbà tí ọ̀tá kò bá borí mi. O ti gbé mi ró nítorí ìwà pípé mi,o sì fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ níwájú rẹ títí lae. Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun Israẹli,lae ati laelae.Amin! Amin! OLUWA yóo máa ṣọ́ ọ, yóo sì dá a sí.Yóo ní ayọ̀ ní ilẹ̀ náà;OLUWA kò ní fi í lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tí ó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn,OLUWA yóo fún un lókun;ní àkókò àìlera OLUWA yóo wo gbogbo àrùn rẹ̀ sàn. Mo ní, “OLUWA, ṣàánú mi kí o sì wò mí sàn;mo ti ṣẹ̀ ọ́.” Àwọn ọ̀tá mi ń ro ibi sí mi, wọ́n ń wí pé,“Nígbà wo ni yóo kú, tí orúkọ rẹ̀ yóo parẹ́?” Tí ọ̀kan bá wá bẹ̀ mí wò,ọ̀rọ̀ tí kò lórí, tí kò nídìíni yóo máa sọ;bẹ́ẹ̀ ni ninu ọkàn rẹ̀, èrò ibi ni yóo máa gbà.Nígbà tí ó bá jáde,yóo máa rò mí kiri. Gbogbo àwọn tí ó kórìíra mijọ ń sọ̀rọ̀ wújẹ́wújẹ́ nípa mi;ohun tó burú jùlọ ni wọ́n ń rò sí mi. Wọ́n ń wí pé, “Àìsàn burúkú ti gbé e dálẹ̀;kò ní dìde mọ́ níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí.” Àní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi tí mo gbẹ́kẹ̀lé,tí ó ń jẹun nílé mi,ó ti kẹ̀yìn sí mí. Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú. Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù,bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń fà sí ọ, Ọlọrun. Bí ọgbẹ́ aṣekúpanini ẹ̀gàn àwọn ọ̀tá mi rí lára mi,nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé,“Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?” Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì?Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín,olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi. Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi,àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè.Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé? Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru,nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé,“Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?” Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti,bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde:bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn,tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́lọ sí ilé Ọlọrun;pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́,láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún. Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì?Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín,olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi,nítorí náà mo ranti rẹláti òkè Herimoni,ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani, ìbànújẹ́ ń já lura wọn,ìdààmú sì ń dà gììrì,wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun. Ní ọ̀sán, OLUWA fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn,ní òru, orin rẹ̀ gba ẹnu mi,àní, adura sí Ọlọrun ìyè mi. Mo bi Ọlọrun, àpáta mi pé,“Kí ló dé tí o fi gbàgbé mi?Kí ló dé tí mò ń ṣọ̀fọ̀ kirinítorí ìnilára ọ̀tá?” Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú. Dá mi láre, Ọlọrun, kí o sì gbèjà mi,lọ́dọ̀ àwọn tí kò mọ̀ Ọ́;gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn ati alaiṣootọ. Nítorí ìwọ ni Ọlọrun tí mo sá di.Kí ló dé tí o fi ta mí nù?Kí ló dé tí mo fi ń ṣọ̀fọ̀ kirinítorí ìnilára ọ̀tá? Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ ati òtítọ́ rẹ jáde,jẹ́ kí wọ́n máa tọ́ mi sọ́nà;jẹ́ kí wọ́n mú mi wá sí orí òkè mímọ́ rẹ,ati ibùgbé rẹ. Nígbà náà ni n óo lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọrun,àní, sọ́dọ̀ Ọlọrun, ayọ̀ ńlá mi.Èmi óo sì yìn ọ́ pẹlu hapu,Ọlọrun, Ọlọrun mi. Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì?Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín,olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi. Adura Ààbò. Ọlọrun, a ti fi etí wa gbọ́,àwọn baba wa sì ti sọ fún wa,nípa àwọn ohun tí o ṣe nígbà ayé wọn,àní, ní ayé àtijọ́: O ti mú kí á sá fún àwọn ọ̀tá wa lójú ogun;àwọn tí ó kórìíra wa sì fi ẹrù wa ṣe ìkógun. O ti ṣe wá bí aguntan lọ́wọ́ alápatà,o sì ti fọ́n wa káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè. O ti ta àwọn eniyan rẹ lọ́pọ̀,o ò sì jẹ èrè kankan lórí wọn. O ti sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wa;a di ẹni ẹ̀sín ati ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ó yí wa ká. O sọ wá di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,ati ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin gbogbo ayé. Àbùkù mi wà lára mi tọ̀sán-tòru,ìtìjú sì ti bò mí. Ọ̀rọ̀ àwọn apẹ̀gàn ati apeni-níjà ṣẹ mọ́ mi lára,lójú àwọn ọ̀tá mi ati àwọn tí ó fẹ́ gbẹ̀san. Gbogbo nǹkan yìí ló ṣẹlẹ̀ sí wa,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbàgbé rẹ,bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹ majẹmu rẹ. Ọkàn wa kò pada lẹ́yìn rẹ,bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìlànà rẹ, sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko,o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀. Ìwọ ni o fi ọwọ́ ara rẹ lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún wọn,tí o sì fi ẹsẹ̀ àwọn baba wa múlẹ̀;o fi ìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè náà,o sì jẹ́ kí ó dára fún àwọn baba wa. Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa,tabi tí a bá bọ oriṣa, ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀?Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn. Ṣugbọn nítorí tìrẹ ni wọ́n fi ń pa wá tọ̀sán-tòru,tí a kà wá sí aguntan lọ́wọ́ alápatà. Para dà, OLUWA, kí ló dé tí o fi ń sùn?Jí gìrì! Má ta wá nù títí lae. Kí ló dé tí o fi ń fi ojú pamọ́?Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìpọ́njú ati ìnira wa? Nítorí pé àwọn ọ̀tá ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀;àyà wa sì lẹ̀ mọ́lẹ̀ típẹ́típẹ́. Gbéra nílẹ̀, kí o ràn wá lọ́wọ́!Gbà wá sílẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Nítorí pé kì í ṣe idà wọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà,kì í ṣe agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun;agbára rẹ ni; àní, agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ,ati ojurere rẹ;nítorí pé inú rẹ dùn sí wọn. Ìwọ ni Ọba mi ati Ọlọrun mi;ìwọ ni o fi àṣẹ sí i pé kí Jakọbu ó ṣẹgun. Nípa agbára rẹ ni a fi bi àwọn ọ̀tá wa sẹ́yìn,orúkọ rẹ ni a fi tẹ àwọn tí ó gbógun tì wá mọ́lẹ̀. Nítorí pé kì í ṣe ọrun mi ni mo gbẹ́kẹ̀lé;idà mi kò sì le gbà mí. Ṣugbọn ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,o sì dójú ti àwọn tí ó kórìíra wa. Ìwọ Ọlọrun ni a fi ń yangàn nígbà gbogbo;a óo sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ títí lae. Sibẹ, o ti ta wá nù o sì ti rẹ̀ wá sílẹ̀,o ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́. Orin Igbeyawo Ọmọ Ọba. Èrò rere kan ń gbé mi lọ́kàn,mò ń kọ orin mi fún ọbaahọ́n mi dàbí gègé akọ̀wé tó mọṣẹ́. Gbọ́, ìwọ ọmọbinrin, ronú kí o sì tẹ́tí sílẹ̀,gbàgbé àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ; ẹwà rẹ yóo sì mú ọ wu ọba;òun ni oluwa rẹ, nítorí náà bu ọlá fún un. Àwọn ará Tire yóo máa fi ẹ̀bùn wá ojurere rẹ,àní, àwọn eniyan tí wọ́n ní ọrọ̀ jùlọ. Yóo máa wá ojurere rẹ,pẹlu oríṣìíríṣìí ọrọ̀.Ọmọ ọbabinrin fi aṣọ wúrà ṣọ̀ṣọ́ jìngbìnnì ninu yàrá rẹ̀, ó wọ aṣọ aláràbarà, a mú un lọ sọ́dọ̀ ọba,pẹlu àwọn wundia ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọn ń sìn ín lọ. Pẹlu ayọ̀ ati inú dídùn ni a fi ń mú wọn lọ,bí wọ́n ṣe ń wọ ààfin ọba. Àwọn ọmọkunrin rẹ ni yóo rọ́pò àwọn baba rẹ;o óo fi wọ́n jọba káàkiri gbogbo ayé. N óo mú kí á máa ki oríkì rẹ láti ìran dé ìran;nítorí náà àwọn eniyan yóo máa yìn ọ́ lae ati laelae. Ìwọ ni o dára jùlọ láàrin àwọn ọkunrin;ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu rẹ,nítorí náà Ọlọrun ti bukun ọ títí ayé. Sán idà rẹ mọ́ ìdí, ìwọ alágbára,ninu ògo ati ọlá ńlá rẹ. Máa gun ẹṣin ìṣẹ́gun lọ ninu ọlá ńlá rẹ,máa jà fún òtítọ́ ati ẹ̀tọ́,kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ fún ọ ní ìṣẹ́gun ńlá. Àwọn ọfà rẹ mú, wọ́n gún àwọn ọ̀tá ọba lọ́kàn,àwọn eniyan ń wó lulẹ̀ níwájú rẹ. Ìjọba tí Ọlọrun fún ọ wà lae ati laelae.Ọ̀pá àṣẹ rẹ, ọ̀pá àṣẹ ẹ̀tọ́ ni. O fẹ́ràn òdodo, o sì kórìíra ìwà ìkànítorí náà ni Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmì òróró yàn ọ́.Àmì òróró ayọ̀ ni ó fi gbé ọ gaju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ lọ. Aṣọ rẹ kún fún òórùn oríṣìíríṣìí turari,láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ni wọ́n tí ń fi ohun èlò ìkọrin olókùn dá ọ lára yá. Àwọn ọmọ ọba wà lára àwọn obinrin inú àgbàlá rẹ,ayaba dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀ṣọ́ sára. Ọlọrun Wà pẹlu Wa. Ọlọrun ni ààbò ati agbára wa,olùrànlọ́wọ́ tí ó wà nítòsí nígbà gbogbo, ní ìgbà ìpọ́njú. “Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọrun.A gbé mi ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,a gbé mi ga ní ayé.” OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa,Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa. Nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà wá bí ayé tilẹ̀ ṣídìí,bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣípò pada, tí wọ́n bọ́ sinu òkun; bí omi òkun tilẹ̀ ń hó, tí ó sì ń ru,tí àwọn òkè ńlá sì ń mì tìtìnítorí agbára ríru rẹ̀. Odò kan wà tí omi rẹ̀ ń mú inú ìlú Ọlọrun dùn,ìlú yìí ni ibùgbé mímọ́ Ọ̀gá Ògo. Ọlọrun wà láàrin rẹ̀,kò ní tú bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣí kúrò;Ọlọrun yóo ràn án lọ́wọ́ ní òwúrọ̀ kutukutu. Inú àwọn orílẹ̀-èdè ń ru,àwọn ìjọba ayé ń gbọ̀n;OLUWA fọhùn, ayé sì yọ́. OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa;Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa. Ẹ wá wo iṣẹ́ OLUWA,irú iṣẹ́ ribiribi tí ó ṣe láyé. Ó dáwọ́ ogun dúró ní gbogbo ayé,ó ṣẹ́ ọrun, ó rún ọ̀kọ̀,ó dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun. Ọba Àwọn Ọba. Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;ẹ kọ orin ayọ̀, ẹ hó sí Ọlọrun. Nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni OLUWA, Ọ̀gá Ògo,Ọba ńlá lórí gbogbo ayé. Ó tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba fún wa,ó sì sọ àwọn orílẹ̀-èdè di àtẹ̀mọ́lẹ̀ fún wa. Òun ni ó yan ilẹ̀ ìní wa fún wa,èyí tí àwọn ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀, fi ń yangàn. A ti gbé Ọlọrun ga pẹlu ìhó ayọ̀,a ti gbé OLUWA ga pẹlu ìró fèrè. Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn;Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọba wa, ẹ kọ orin ìyìn! Nítorí Ọlọrun ni Ọba gbogbo ayé;Ẹ fi gbogbo ohun èlò ìkọrin kọ orin ìyìn! Ọlọrun jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;Ó gúnwà lórí ìtẹ́ mímọ́ rẹ̀. Àwọn ìjòyè orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọpẹlu àwọn eniyan Ọlọrun Abrahamu.Ọlọrun ni aláṣẹ gbogbo ayé;òun ni ọlọ́lá jùlọ! OLUWA Tóbi. OLUWA tóbi, ó sì yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọní ìlú Ọlọrun wa. Ọlọrun, ìyìn rẹ tàn ká,bí orúkọ rẹ ṣe tàn dé òpin ayé,iṣẹ́ rere kún ọwọ́ rẹ. Jẹ́ kí inú òkè Sioni kí ó dùn,kí gbogbo Juda sì máa yọ̀nítorí ìdájọ́ rẹ. Ẹ rìn yí Sioni po; ẹ yí i ká;ẹ ka àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀; ẹ ṣàkíyèsí odi rẹ̀;ẹ wọ inú gbogbo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lọ,kí ẹ lè ròyìn fún ìran tí ń bọ̀ pe: “Ọlọrun yìí ni Ọlọrun wa,lae ati laelae.Òun ni yóo máa ṣe amọ̀nà wa títí lae.” Òkè mímọ́ rẹ̀, tí ó ga, tí ó sì lẹ́wà,ni ayọ̀ gbogbo ayé.Òkè Sioni, ní àríwá, lọ́nà jíjìn réré,ìlú ọba ńlá. Ninu ilé ìṣọ́ ìlú náà, Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ hàn bí ibi ìsádi. Wò ó! Àwọn ọba kó ara wọn jọ;wọ́n jùmọ̀ gbógun tì í. Nígbà tí wọ́n fojú kàn án, ẹnu yà wọ́n,ìpayà mú wọn, wọ́n sì sá; ìwárìrì mú wọn níbẹ̀;ìrora sì bá wọn bí obinrin tí ń rọbí. Ó fọ́ wọn bí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn tií fọ́ ọkọ̀ Taṣiṣi. Bí a ti gbọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí,ní ìlú OLUWA àwọn ọmọ ogun,ní ìlú Ọlọrun wa:Ọlọrun fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae. Ninu tẹmpili rẹ, Ọlọrun,à ń ṣe àṣàrò lórí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Ìwà Òmùgọ̀ ni Igbẹkẹle Ọrọ̀. Ẹ gbọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè!Ẹ dẹtí sílẹ̀, gbogbo aráyé, Yóo rí i pé ikú a máa pa ọlọ́gbọ́n,òmùgọ̀ ati òpè a sì máa rọ̀run;wọn a sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn. Ibojì wọn ni ilé wọn títí lae,ibẹ̀ ni ibùgbé wọn títí ayérayé,wọn ìbáà tilẹ̀ ní ilẹ̀ ti ara wọn. Eniyan kò lè máa gbé ninu ọlá rẹ̀ títí ayé,bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo kú. Ìpín àwọn tí ó ní igbẹkẹle asán nìyí,òun sì ni èrè àwọn tí ọrọ̀ wọn tẹ́ lọ́rùn. Ikú ni ìpín wọn bí àgùntàn lásánlàsàn,ikú ni yóo máa ṣe olùṣọ́ wọn;ibojì ni wọ́n sì ń lọ tààrà.Wọn yóo jẹrà, ìrísí wọn óo sì parẹ́,Àwọn olódodo yóo jọba lórí wọn ní òwúrọ̀,ibojì ni yóo sì máa jẹ́ ilé wọn. Ṣugbọn Ọlọrun yóo ra ẹ̀mí mi pada lọ́wọ́ ikúnítorí pé yóo gbà mí. Má ba ara jẹ́ bí ẹnìkan bá di olówó,tí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Nítorí pé ní ọjọ́ tí ó bá kú,kò ní mú ohunkohun lọ́wọ́ lọ;dúkìá rẹ̀ kò sì ní bá a wọ ibojì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí ó wà láàyè,ó rò pé Ọlọrun bukun òun,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé a máa yin eniyannígbà tí nǹkan bá ń dára fún un, yóo kú bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti kú,kò sì ní fojú kan ìmọ́lẹ̀ mọ́. ati mẹ̀kúnnù àtọlọ́lá,àtolówó ati talaka! Eniyan kò lè máa gbé inú ọlá rẹ̀ títí ayé;bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo ku. Ẹnu mi yóo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n;àṣàrò ọkàn mi yóo sì jẹ́ ti òye. N óo tẹ́tí sílẹ̀ sí òwe;n óo sì fi hapu túmọ̀ rẹ̀. Kí ló dé tí n óo fi bẹ̀rù ní àkókò ìyọnu,nígbà tí iṣẹ́ ibi àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi bá yí mi ká, àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,tí wọ́n sì ń yangàn nítorí wọ́n ní ọrọ̀ pupọ? Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó le ra ara rẹ̀ pada,tabi tí ó lè san owó ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ fún Ọlọrun; nítorí pé ẹ̀mí eniyan níye lórí pupọ.Kò sí iye tí eniyan ní tí ó le kájú rẹ̀, tí eniyan lè máa fi wà láàyè títí lae,kí ó má fojú ba ikú. Adura Ààbò. Fetí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA;kíyèsí ìmí ẹ̀dùn mi. Dá wọn lẹ́bi, Ọlọrun, kí o sì fìyà jẹ wọ́n;jẹ́ kí ìgbìmọ̀pọ̀ wọn ó gbé wọn ṣubú.Ta wọ́n nù nítorí ọ̀pọ̀ ìrékọjá wọn,nítorí pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. Ṣugbọn jẹ́ kí inú gbogbo àwọn tí ó sá di ọ́ ó dùn,kí wọn ó máa kọrin ayọ̀ títí lae.Dáàbò bò wọ́n,kí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ sì máa yọ̀ ninu rẹ. Nítorí ìwọ OLUWA a máa bukun àwọn olódodo;ò sì máa fi ojurere rẹ tí ó dàbí apata dáàbò bò wọ́n. Fetí sí igbe mi,Ọba mi ati Ọlọrun mi,nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí. OLUWA, o óo gbọ́ ohùn mi ní òwúrọ̀,ní òwúrọ̀ ni n óo máa sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún ọ;èmi óo sì máa ṣọ́nà. Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọrun tí inú rẹ̀ dùn sí ìwà burúkú;àwọn ẹni ibi kò sì lè bá ọ gbé. Àwọn tí ń fọ́nnu kò lè dúró níwájú rẹ;o kórìíra gbogbo àwọn aṣebi. O máa ń pa àwọn òpùrọ́ run;OLUWA, o kórìíra àwọn apani ati ẹlẹ́tàn. Ṣugbọn nípa ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,èmi óo wọ inú ilé rẹ;n óo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ wólẹ̀, n óo sì kọjúsí tẹmpili mímọ́ rẹ. OLUWA, tọ́ mi sọ́nà òdodo rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi;jẹ́ kí ọ̀nà rẹ hàn kedere níwájú mi. Nítorí kò sí òtítọ́ kan lẹ́nu wọn;ìparun ni ó wà ninu ọkàn wọn.Isà òkú tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn;ẹnu wọn kún fún ìpọ́nni ẹ̀tàn. Ìsìn Tòótọ́. OLUWA, Ọlọrun Alágbára ti sọ̀rọ̀:ó ké sí gbogbo ayéláti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Nítorí èmi ni mo ni gbogbo ẹran inú igbó,tèmi sì ni gbogbo mààlúù tó wà lórí ẹgbẹrun òkè. Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ni mo mọ̀,tèmi sì ni gbogbo nǹkan tí ń rìn ninu pápá. “Bí ebi bá tilẹ̀ pa mí, ẹ̀yin kọ́ ni n óo sọ fún,nítorí èmi ni mo ni gbogbo ayé ati àwọn nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀. Ṣé èmi a máa jẹ ẹran akọ mààlúù?Àbí mà máa mu ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́? Ọpẹ́ ni kí ẹ fi rúbọ sí Ọlọrun,kí ẹ sì máa san ẹ̀jẹ́ yín fún Ọ̀gá Ògo. Ẹ ké pè mí ní ọjọ́ ìṣòro;n óo gbà yín, ẹ óo sì yìn mí lógo.” Ṣugbọn Ọlọrun bi àwọn eniyan burúkú pé,“Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti máa ka àwọn òfin mi,tabi láti máa mú ẹnu ba ìlànà mi? Nítorí ẹ kórìíra ẹ̀kọ́;ẹ sì ti ta àṣẹ mi nù. Tí ẹ bá rí olè, ẹ̀yin pẹlu rẹ̀ a dọ̀rẹ́;ẹ sì ń bá àwọn panṣaga kẹ́gbẹ́. “Ọ̀rọ̀ ibi dùn lẹ́nu yín pupọ;ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sì yọ̀ létè yín. Ọlọrun yọ bí ọjọ́ láti Sioni,ìlú tó dára, tó lẹ́wà. Ẹ̀ ń jókòó sọ̀rọ̀ arakunrin yín níbi:ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ nípa ọmọ ìyá yín. Gbogbo nǹkan wọnyi ni ẹ ti ṣe tí mo sì dákẹ́;ẹ wá ń rò ninu yín pé, èmi yín rí bákan náà.Ṣugbọn nisinsinyii mò ń ba yín wí,mo sì ń fi ẹ̀sùn kàn yín. “Nítorí náà, ẹ fi èyí lékàn, ẹ̀yin tí ẹ gbàgbé Ọlọrun,kí n má baà fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kò sì ní sí ẹni tí yóo gbà yín kalẹ̀. Ẹni tí ó bá mu ọpẹ́ wá, tí ó fi rúbọ sí mi, ni ó bu ọlá fún mi;ẹni tí ó bá sì rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni èmi Ọlọrun yóo gbà là.” Ọlọrun wa ń bọ̀, kò dákẹ́:iná ajónirun ń jó níwájú rẹ̀;ìjì líle sì ń jà yí i ká. Ó ké sí ọ̀run lókè;ó pe ayé pẹlu láti gbọ́ ìdájọ́ tí yóo ṣe fún àwọn eniyan rẹ̀. Ó ní, “Ẹ kó àwọn olùfọkànsìn mi jọ sọ́dọ̀ mi,àwọn tí wọ́n ti fi ẹbọ bá mi dá majẹmu!” Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀ péỌlọrun ni onídàájọ́. “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, n óo sọ̀rọ̀,Israẹli, n óo takò yín.Èmi ni Ọlọrun, Ọlọrun yín. N kò ba yín wí nítorí ẹbọ rírú;nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń rú ẹbọ sísun sí mi. N kò ní gba akọ mààlúù lọ́wọ́ yín,tabi òbúkọ láti agbo ẹran yín. Adura Ìdáríjì . Ṣàánú mi, Ọlọrun, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;nítorí ọ̀pọ̀ àánú rẹ pa ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́. Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọrun,kí o sì fi ẹ̀mí ọ̀tun ati ẹ̀mí ìṣòótọ́ sí mi lọ́kàn. Má ta mí nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ,má sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi. Dá ayọ̀ ìgbàlà rẹ pada fún mi,kí o sì fi ẹ̀mí àtiṣe ìfẹ́ rẹ gbé mi ró. Nígbà náà ni n óo máa kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀nà rẹ,àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo sì máa yipada sí ọ. Gbà mí lọ́wọ́ ẹ̀bi ìpànìyàn, Ọlọrun,ìwọ Ọlọrun, Olùgbàlà mi,n óo sì máa fi orin kéde iṣẹ́ rere rẹ. OLUWA, là mí ní ohùn,n óo sì máa ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ. Bí ó bá jẹ́ pé o fẹ́ ẹbọ ni, ǹ bá mú wá fún ọ;ṣugbọn o ò tilẹ̀ fẹ́ ẹbọ sísun. Ẹbọ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ ìwọ Ọlọrun ni ẹ̀mí ìròbìnújẹ́,ọkàn ìròbìnújẹ́ ati ìrònúpìwàdà ni ìwọ kì yóo gàn. Jẹ́ kí ó dára fún Sioni ninu ìdùnnú rẹ;tún odi Jerusalẹmu mọ. Nígbà náà ni inú rẹ yóo dùn sí ẹbọ tí ó tọ́,ẹbọ sísun, ati ẹbọ tí a sun lódidi;nígbà náà ni a óo fi akọ mààlúù rúbọ lórí pẹpẹ rẹ. Wẹ̀ mí mọ́ kúrò ninu àìdára mi,kí o sì wẹ̀ mí kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ mi! Nítorí mo mọ ibi tí mo ti ṣẹ̀,nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi sì wà níwájú mi. Ìwọ nìkan, àní, ìwọ nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ̀,tí mo ṣe ohun tí ó burú lójú rẹ,kí ẹjọ́ rẹ lè tọ́ nígbà tí o bá ń dájọ́,kí ọkàn rẹ lè mọ́ nígbà tí o bá ń ṣe ìdájọ́. Dájúdájú, ninu àìdára ni a bí mi,ninu ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mi sì lóyún mi. O fẹ́ràn òtítọ́ inú;nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi. Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́;wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ. Fún mi ní ayọ̀ ati inú dídùn,kí gbogbo egungun mi tí ó ti rún lè máa yọ̀. Mójú kúrò lára ẹ̀ṣẹ̀ mi,kí o sì pa gbogbo àìdára mi rẹ́. Ìdájọ́ ati Oore Ọ̀fẹ́ Ọlọrun . Ìwọ alágbára, kí ló dé tí o fi ń fọ́nnu,kí ló dé tí ò ń fọ́nnu tọ̀sán-tòru?Ẹni ìtìjú ni ọ́ lójú Ọlọrun. Ò ń pète ìparun;ẹnu rẹ dàbí abẹ tí ó mú, ìwọ alárèékérekè. O fẹ́ràn ibi ju ire lọ,o sì fẹ́ràn irọ́ ju òtítọ́ lọ. O fẹ́ràn gbogbo ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́,Ìwọ ẹlẹ́tàn! Nítòótọ́ Ọlọrun óo bá ọ kanlẹ̀,yóo gbá ọ mú, yóo sì fà ọ́ já kúrò ninu ilé rẹ;yóo fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Nígbà tí àwọn olódodo bá rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,wọn óo fi rẹ́rìn-ín, wọn óo sì wí pé, “Wo ẹni tí ó kọ̀, tí kò fi Ọlọrun ṣe ààbò rẹ̀,ṣugbọn ó gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀,ati jamba tí ó ń ta fún ẹlòmíràn.” Ṣugbọn èmi dàbí igi olifi tútùtí ń dàgbà ninu ilé OLUWA,mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọrun tí kì í yẹ̀, lae ati laelae. N óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae,nítorí ohun tí o ṣe,n óo máa kéde orúkọ rẹ níwájú àwọn olùfọkànsìn rẹ,nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀. Èrè Òmùgọ̀. Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé,“Kò sí Ọlọrun.”Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni wọ́n ń ṣe,kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere. Ọlọrun bojú wo àwọn ọmọ eniyan láti ọ̀run wá,ó ń wò ó bí àwọn kan bá wà tí òye yé,àní, bí àwọn kan bá wà tí ń wá Ọlọrun. Gbogbo wọn ni ó ti yapa;tí wọn sì ti bàjẹ́,kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere,kò sí, bó tilẹ̀ jẹ́ ẹnìkan ṣoṣo. Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni?Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun,àní àwọn tí kì í ké pe Ọlọrun. Ẹ wò wọ́n, bí wọ́n ṣe wà ninu ẹ̀rù ńlá,ẹ̀rù tí kò tíì sí irú rẹ̀ rí!Nítorí Ọlọrun yóo fọ́n egungun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ká;ojú óo tì wọ́n, nítorí Ọlọrun ti kọ̀ wọ́n. Ìbá ti dára tó, kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá!Nígbà tí Ọlọrun bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada,Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn. Adura Ààbò . Fi agbára orúkọ rẹ gbà mí, Ọlọrun,fi ipá rẹ dá mi láre. Gbọ́ adura mi, Ọlọrun;tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Nítorí pé àwọn agbéraga dìde sí mi,àwọn ìkà, aláìláàánú sì ń lépa ẹ̀mí mi;wọn kò bìkítà fún Ọlọrun. Ṣugbọn Ọlọrun ni olùrànlọ́wọ́ mi,OLUWA ni ó gbé ẹ̀mí mi ró. Yóo san ẹ̀san ibi fún àwọn ọ̀tá mi;OLUWA, nítorí òtítọ́ rẹ, pa wọ́n run. N óo rú ẹbọ ọrẹ àtinúwá sí ọ,n óo máa yin orúkọ rẹ, OLUWA,nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀. O ti yọ mí ninu gbogbo ìṣòro mi,mo sì ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi. Adura Ẹni tí Ọ̀rẹ́ Dà. Tẹ́tí sí adura mi, Ọlọrun,má sì fara pamọ́ nígbà tí mo bá ń bẹ̀bẹ̀. Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń yí orí odi rẹ̀ ká;ìwà ìkà ati ìyọnu ni ó sì pọ̀ ninu rẹ̀. Ìparun wà ninu rẹ̀;ìnilára ati ìwà èrú kò sì kúrò láàrin ìgboro rẹ̀. Bí ó bá ṣe pé ọ̀tá ní ń gàn mí,ǹ bá lè fara dà á.Bí ó bá ṣe pé ẹni tí ó kórìíra mi ní ń gbéraga sí mi,ǹ bá fara pamọ́ fún un. Ṣugbọn ìwọ ni; ìwọ tí o jẹ́ irọ̀ mi,alábàárìn mi, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́. À ti jọ máa sọ ọ̀rọ̀ dídùndídùn pọ̀ rí;a sì ti jọ rìn ní ìrẹ́pọ̀ ninu ilé Ọlọrun. Jẹ́ kí ikú jí àwọn ọ̀tá mi pa;kí wọ́n lọ sinu isà òkú láàyè;kí wọ́n wọ ibojì lọ pẹlu ìpayà. Ṣugbọn èmi ké pe Ọlọrun;OLUWA yóo sì gbà mí. Mò ń ráhùn tọ̀sán-tòru,mo sì ń kérora; OLUWA óo gbọ́ ohùn mi. Yóo yọ mí láìfarapa,ninu ogun tí mò ń jà,nítorí ọ̀pọ̀ ni àwọn tí wọ́n dojú kọ mí,tí wọn ń bá mi jà. Ọlọrun tí ó gúnwà láti ìgbàanì yóo gbọ́,yóo sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,nítorí pé wọn kò pa ìwà wọn dà,wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọrun. Fetí sí mi, kí o sì dá mi lóhùn;ìṣòro ti borí mi. Alábàárìn mi gbógun ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀,ó yẹ àdéhùn rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn ju oyin lọ,bẹ́ẹ̀ sì ni ìjà ni ó wà lọ́kàn rẹ̀;ọ̀rọ̀ rẹ̀ tutù ju omi àmù lọ,ṣugbọn idà aṣekúpani ni. Kó gbogbo ìṣòro rẹ lé OLUWA lọ́wọ́,yóo sì gbé ọ ró;kò ní jẹ́ kí á ṣí olódodo ní ipò pada. Ṣugbọn ìwọ, Ọlọrun, o óo sọ àwọn apaniati àwọn alárèékérekè, sinu kòtò ìparun;wọn kò ní lo ìdajì ọjọ́ ayé wọn.Ṣugbọn èmi óo gbẹ́kẹ̀lé ọ. Ìhàlẹ̀ ọ̀tá bà mí ninu jẹ́,nítorí ìnilára àwọn eniyan burúkú;wọ́n kó ìyọnu bá mi,wọ́n ń bínú mi, inú wọn sì dùn láti máa bá mi ṣọ̀tá. Ọkàn mi wà ninu ìrora,ìpayà ikú ti dé bá mi. Ẹ̀rù ati ìwárìrì dà bò mí,ìpayà sì bò mí mọ́lẹ̀. Mo ní, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!Ǹ bá fò lọ, ǹ bá lọ sinmi. Áà! Ǹ bá lọ jìnnà réré,kí n lọ máa gbé inú ijù; ǹ bá yára lọ wá ibi ààbòkúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ líle ati ìjì.” Da èrò wọn rú, OLUWA,kí o sì dà wọ́n lédè rú;nítorí ìwà ipá ati asọ̀ pọ̀ ninu ìlú. Adura Igbẹkẹle Ọlọrun. Ṣàánú mi, Ọlọrun, nítorí pé àwọn eniyan ń lépa mi;ọ̀tá gbógun tì mí tọ̀sán-tòru. Ọlọrun, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,OLUWA, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀; Ọlọrun ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù.Kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe? Èmi óo san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ, Ọlọrun;n óo sì mú ẹbọ ọpẹ́ wá fún ọ. Nítorí pé o ti gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ ikú,o gbà mí, o kò jẹ́ kí n kọsẹ̀,kí n lè máa rìn níwájú Ọlọrunninu ìmọ́lẹ̀ ìyè. Àwọn ọ̀tá ń lépa mi tọ̀sán-tòru,ọpọlọpọ ní ń bá mi jà tìgbéraga-tìgbéraga. Nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà mí,èmi yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ. Ọlọrun, mo yìn ọ́ fún ọ̀rọ̀ rẹ,ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù;kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe? Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń da ọ̀rọ̀ mi rú;ibi ni gbogbo èrò tí wọn ń gbà sí mi. Wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n sápamọ́,wọ́n ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi,bí wọn ṣé ń dọdẹ ẹ̀mí mi. Nítorí náà, san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn;ninu ibinu rẹ, Ọlọrun, ré àwọn eniyan yìí lulẹ̀. O sá mọ gbogbo ìdààmú mi;ati bí omijé mi ti pọ̀ tó,wọ́n ṣá wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé rẹ. A óo lé àwọn ọ̀tá mi padaní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́.Mo mọ̀ dájú pé Ọlọrun ń bẹ fún mi. Adura Ìrànlọ́wọ́ . Ṣàánú mi, Ọlọrun, ṣàánú mi,nítorí ìwọ ni ààbò mi;abẹ́ òjìji apá rẹ ni n óo fi ṣe ààbò mi,títí gbogbo àjálù wọnyi yóo fi kọjá. Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ,òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé. Mo ké pe Ọlọrun Ọ̀gá Ògo,Ọlọrun tí ó mú èrò rẹ̀ ṣẹ fún mi. Yóo ranṣẹ láti ọ̀run wá, yóo gbà mí là,yóo dójú ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi.Ọlọrun yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ati òtítọ́ rẹ̀ hàn! Ààrin àwọn kinniun ni mo dùbúlẹ̀ sí,àwọn tí ń jẹ eniyan ní ìjẹ ìwọ̀ra;eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ ati ọfà,ahọ́n wọn sì dàbí idà. Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé. Wọ́n dẹ àwọ̀n sí ojú ọ̀nà mi;ìpọ́njú dorí mi kodò.Wọ́n gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,ṣugbọn àwọn fúnra wọn ni wọ́n jìn sí i. Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun,ọkàn mi dúró ṣinṣin!N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́. Jí, ìwọ ọkàn mi!Ẹ jí, ẹ̀yin ohun èlò orin, ati hapu,èmi alára náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu. OLUWA, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ láàrin àwọn eniyan;n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Kí Ọlọrun jẹ Ìkà níyà. Ǹjẹ́ ìpinnu tí ẹ̀ ń ṣe tọ̀nà, ẹ̀yin aláṣẹ? Ǹjẹ́ ẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan ní ọ̀nà ẹ̀tọ́? Olódodo yóo yọ̀ nígbà tí ẹ̀san bá ń ké,yóo fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan burúkú. Àwọn eniyan yóo wí nígbà náà pé,“Nítòótọ́, èrè ń bẹ fún olódodo;nítòótọ́, Ọlọrun ń bẹ tí ń ṣe ìdájọ́ ayé.” Rárá o! Ibi ni ẹ̀ ń fi ọkàn yín rò,iṣẹ́ burúkú ni ẹ sì ń fi ọwọ́ yín ṣe láyé. Láti inú oyún ni àwọn eniyan burúkú ti ṣìnà,láti ọjọ́ tí a ti bí wọn ni wọ́n tí ń ṣìṣe,tí wọn ń purọ́. Wọ́n ní oró bí oró ejò,wọ́n dití bíi paramọ́lẹ̀ tí ó di etí ara rẹ̀, kí ó má baà gbọ́ ohùn afunfèrè,tabi ìpè adáhunṣe. Kán eyín mọ́ wọn lẹ́nu, Ọlọrun;OLUWA! Yọ ọ̀gàn àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun. Jẹ́ kí wọ́n rá, kí wọn ṣàn lọ bí omi;kí á tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi koríko, kí wọn sì rọ. Kí wọn dàbí ìgbín tí a tẹ̀ ní àtẹ̀rẹ́, tí ó domi,ati bí òkúmọ tí kò fojú kan ìmọ́lẹ̀ ayé rí. Lójijì, a ó ké eniyan burúkú lulẹ̀;ìjì ibinu Ọlọrun yóo sì gbá wọn lọ. Adura Ààbò . Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Ọlọrun mi;dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì mí. Ọlọrun mi óo wá sọ́dọ̀ mi ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀;Ọlọrun óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi. Má pa wọ́n, kí àwọn eniyan mi má baà gbàgbé;fi ọwọ́ agbára rẹ mì wọ́n,ré wọn lulẹ̀, OLUWA, ààbò wa! Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn dá,àní, nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ,jẹ́ kí ìgbéraga wọn kó bá wọn.Nítorí èpè tí wọ́n ṣẹ́ ati irọ́ tí wọ́n pa, fi ibinu pa wọ́n run.Pa wọ́n run kí wọn má sí mọ́,kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé Ọlọrun jọba lórí Jakọbu,ati títí dé òpin ayé. Ní alaalẹ́ wọn á pada wáwọn á máa hu bí ajá, wọn á sì máa kiri ìlú. Wọn á máa fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀, wọn á máa wá oúnjẹ kiri,bí wọn ò bá sì yó wọn á máa kùn. Ṣugbọn èmi ó kọrin ìyìn agbára rẹ;n óo kọrin sókè lówùúrọ̀, nípa ìfẹ́ rẹ tíkì í yẹ̀.Nítorí ìwọ ni o ti jẹ́ odi miìwọ sì ni ààbò mi nígbà ìpọ́njú. Ọlọrun, agbára mi, n óo kọ orin ìyìn fún ọ,nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi,Ọlọrun tí ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn mí. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn aṣebi,kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn apànìyàn. Wò ó bí wọ́n ṣe lúgọ dè mí!OLUWA, àwọn jàǹdùkú eniyan kó ara wọn jọláti pa mí lára, láìṣẹ̀, láìrò. Láìjẹ́ pé mo ṣẹ̀, wọ́n ń sáré kiri, wọ́n múra dè mí.Paradà, wá ràn mí lọ́wọ́, kí o sì rí i fúnra rẹ. Ìwọ, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,Ọlọrun Israẹli,jí gìrì, kí o jẹ gbogbo orílẹ̀-èdè níyà;má da ẹnìkan kan sí ninu àwọn tí ń fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ pète ibi. Ní alaalẹ́, wọn á pada wá,wọn á máa hu bí ajá, wọn a sì máa kiri ìlú. Ẹ gbọ́ ohun tí wọn ń sọ jáde lẹ́nu,ẹ wo ahọ́n wọn bí idà;wọ́n sì ń wí ninu ara wọn pé, “Ta ni yóo gbọ́ ohun tí à ń sọ?” Ṣugbọn ìwọ OLUWA ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín,o sì ń fi gbogbo orílẹ̀-èdè ṣe yẹ̀yẹ́. Ọlọrun, agbára mi, ojú rẹ ni mò ń wò,nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi. Adura nígbà ìyọnu. OLUWA, má fi ibinu bá mi wí;má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà. Ojú yóo ti gbogbo àwọn ọ̀tá mi;ìdààmú ńlá yóo bá wọn,wọn óo sá pada,ojú yóo sì tì wọ́n lójijì. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí àárẹ̀ mú ọkàn mi,OLUWA, wò mí sàn nítorí ara ń ni mí dé egungun. Ọkàn mi kò balẹ̀ rárá,yóo ti pẹ́ tó, OLUWA, yóo ti pẹ́ tó? OLUWA, pada wá gbà mí,gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Nítorí kò sí ẹni tí yóo ranti rẹ lẹ́yìn tí ó bá ti kú.Àbí, ta ló lè yìn ọ́ ninu isà òkú? Ìkérora dá mi lágara:ní òròòru ni mò ń fi omijé rẹ ẹní mi;tí mò ń sunkún tí gbogbo ibùsùn mi ń tutù. Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,agbára káká ni mo fi lè ríran nítorí ìnilára àwọn ọ̀tá. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi,nítorí OLUWA ti gbọ́ ìró ẹkún mi. OLUWA ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi,OLUWA ti tẹ́wọ́gba adura mi. Adura fún Ìgbàlà . Ọlọrun, o ti kọ̀ wá sílẹ̀,o ti wó odi wa;o ti bínú, dákun, mú wa bọ̀ sípò. Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀?Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́. Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa,nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan. Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun a óo ṣe akin,nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀. O ti mú kí ilẹ̀ mì tìtì;o ti mú kí ó yanu;dí gbogbo ibi tí ilẹ̀ ti ya, nítorí pé ó ń mì. O ti jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ ní ọpọlọpọ ìnira,o ti fún wa ní ọtí mu tóbẹ́ẹ̀ tí à ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n. O ti ta àsíá ogun fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,kí wọ́n baà lè rí ààbò lọ́wọ́ ọfà ọ̀tá. Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là,fi ọwọ́ agbára rẹ ṣẹgun fún wa,kí o sì dá wa lóhùn. Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀,ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu,n óo sì pín àfonífojì Sukotu. Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi,Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi. Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi;lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé;n óo sì hó ìhó ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Filistia.” Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà?Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu? Adura Ààbò. Gbọ́ igbe mi, Ọlọrun,fetí sí adura mi. Láti ọ̀nà jíjìn réré ni mo ti ké pè ọ́,nígbà tí àárẹ̀ mú mi.Tọ́ mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ, nítorí ìwọ ni ààbò mi,ìwọ ni ilé ìṣọ́ tí ó lágbáraláti dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tá. Jẹ́ kí n máa gbé inú àgọ́ rẹ títí lae,kí n lè máa wà láìléwu lábẹ́ ààbò ìyẹ́ rẹ. Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti gbọ́ ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́;o ti fún mi ní ogún tí o pèsè fún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba ó gùn;kí ó pẹ́ láyé kánrinkése. Kí ó máa gúnwà níwájú Ọlọrun títí lae;máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ ṣọ́ ọ. Bẹ́ẹ̀ ni n óo máa kọ orin ìyìn orúkọ rẹ títí lae,nígbà tí mo bá ń san ẹ̀jẹ́ mi lojoojumọ. Ọlọrun ni Ààbò Wa. Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé;ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìgbàlà mi ti wá. Má gbẹ́kẹ̀lé ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà,má sì fi olè jíjà yangàn;bí ọrọ̀ bá ń pọ̀ sí i, má gbé ọkàn rẹ lé e. Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ níbìkan,mo sì ti gbọ́ ọ bí ìgbà mélòó kan pé,Ọlọrun ló ni agbára; ati pé, tìrẹ, OLUWA ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.Ò máa san ẹ̀san fún eniyangẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí. Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi,òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò. Yóo ti pẹ́ tó, tí gbogbo yín yóo dojú kọ ẹnìkan ṣoṣo, láti pa,ẹni tí kò lágbára ju ògiri tí ó ti fẹ́ wó lọ, tabi ọgbà tí ó fẹ́ ya? Wọ́n fẹ́ ré e bọ́ láti ipò ọlá rẹ̀.Inú wọn a máa dùn sí irọ́.Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,ṣugbọn ní ọkàn wọn, èpè ni wọ́n ń ṣẹ́. Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé,nítorí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá. Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi,òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò. Ọwọ́ Ọlọrun ni ìgbàlà ati ògo mi wà;òun ni àpáta agbára mi ati ààbò mi. Ẹ gbẹ́kẹ̀lé e nígbà gbogbo, ẹ̀yin eniyan;ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín palẹ̀ níwájú rẹ̀;OLUWA ni ààbò wa. Afẹ́fẹ́ lásán ni àwọn mẹ̀kúnnù;ìtànjẹ patapata sì ni àwọn ọlọ́lá;bí a bá gbé wọn lé ìwọ̀n, wọn kò lè tẹ̀wọ̀n;àpapọ̀ wọn fúyẹ́ ju afẹ́fẹ́ lọ. Wíwá Ọlọrun . Ọlọrun, ìwọ ni Ọlọrun mi, mò ń wá ọ,ọkàn rẹ ń fà mí;bí ilẹ̀ tí ó ti ṣá, tí ó sì gbẹṣe máa ń kóǹgbẹ omi. A ó fi idà pa wọ́n lójú ogun,ẹranko ni yóo sì jẹ òkú wọn. Ṣugbọn ọba yóo máa yọ̀ ninu Ọlọrun;gbogbo àwọn tí ń fi orúkọ OLUWA búrayóo máa fògo fún un;ṣugbọn a ó pa àwọn òpùrọ́ lẹ́nu mọ́. Mo ti ń wò ọ́ ninu ilé mímọ́ rẹ,mo ti rí agbára ati ògo rẹ. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára ju ìyè lọ,n óo máa yìn ọ́. N óo máa yìn ọ́ títí ayé mi;n óo máa tẹ́wọ́ adura sí ọ. Ẹ̀mí mi yóo ní ànító ati àníṣẹ́kù;n óo sì fi ayọ̀ kọ orin ìyìn sí ọ. Nígbà tí mo bá ranti rẹ lórí ibùsùn mi,tí mo bá ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní gbogbo òru; nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi,lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ ni mò ń fi ayọ̀ kọrin. Ẹ̀mí mi rọ̀ mọ́ ọ;ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni ó gbé mi ró. Ṣugbọn àwọn tí ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí miyóo sọ̀kalẹ̀ lọ sinu isà òkú. Adura Ààbò. Ọlọrun, gbọ́ ìráhùn mi;pa mí mọ́ lọ́wọ́ ìdẹ́rùbà ọ̀tá; Kí àwọn olódodo máa yọ̀ ninu OLUWA,kí wọ́n sì máa wá ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀!Kí gbogbo ẹni pípé máa ṣògo. dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan burúkú;kó mi yọ lọ́wọ́ ète àwọn aṣebi. Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ burúkú bí ẹni ta ọfà; wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí aláìṣẹ̀ láti ibùba wọn,láìbẹ̀rù, wọ́n ń ta ọfà ọ̀rọ̀ sí i lójijì. Wọ́n wonkoko mọ́ ète burúkú wọn;wọ́n ń gbìmọ̀ àtidẹ okùn sílẹ̀ níkọ̀kọ̀,wọ́n ń rò lọ́kàn wọn pé, “Ta ni yóo rí wa? Ta ni yóo wá ẹ̀ṣẹ̀ wa rí?Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí ni a ti fi pète.”Áà, inú ọmọ eniyan jìn! Ṣugbọn Ọlọrun yóo ta wọ́n lọ́fà;wọn óo fara gbọgbẹ́ lójijì. Yóo pa wọ́n run nítorí ohun tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ;gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn ni yóo máa mirí nítorí wọn. Ẹ̀rù yóo sì ba gbogbo eniyan;wọn yóo máa sọ ohun tí Ọlọrun ti gbé ṣe,wọn yóo sì máa ronú nípa iṣẹ́ rẹ̀. Ìyìn ati Ọpẹ́. Ọlọrun, ìwọ ni ìyìn yẹ ní Sioni,ìwọ ni a óo san ẹ̀jẹ́ wa fún, O bomi rin poro oko rẹ̀ lọpọlọpọ,o ṣètò àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀;o rọ òjò tó mú kí ilẹ̀ rọ̀,o sì mú kí ohun ọ̀gbìn rẹ̀ dàgbà. O mú kí ìkórè oko pọ̀ yanturu ní òpin ọdún;gbogbo ipa ọ̀nà rẹ sì kún fún ọpọlọpọ ìkórè oko. Gbogbo pápá oko kún fún ẹran ọ̀sìn,àwọn ẹ̀gbẹ́ òkè sì kún fún ohun ayọ̀, ẹran ọ̀sìn bo pápá oko bí aṣọ,ọkà bo gbogbo àfonífojì, ó sì so jìngbìnnì,wọ́n ń hó, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀. ìwọ tí ń gbọ́ adura!Ọ̀dọ̀ rẹ ni gbogbo eniyan ń bọ̀, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá borí wa,ìwọ a máa dáríjì wá. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o yàn,tí o mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,láti máa gbé inú àgbàlá rẹ.Àwọn ire inú ilé rẹ yóo tẹ́ wa lọ́rùn,àní, àwọn ire inú tẹmpili mímọ́ rẹ! Iṣẹ́ òdodo tí ó bani lẹ́rù ni o fi dá wa lóhùn,Ọlọrun olùgbàlà wa.Ìwọ ni gbogbo àwọn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé gbẹ́kẹ̀lé,ati àwọn tí wọn wà lórí omi òkun ní ọ̀nà jíjìn réré. Ìwọ tí o fi agbára fi ìdí àwọn òkè ńlá múlẹ̀;tí o sì fi agbára di ara rẹ ní àmùrè. O mú híhó òkun dákẹ́ jẹ́ẹ́,ariwo ìgbì wọn rọlẹ̀ wọ̀ọ̀;o sì paná ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan. Àwọn tí ń gbé ìpẹ̀kun ayé sì ń bẹ̀rùnítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ;o mú kí àwọn eniyan, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀, hó ìhó ayọ̀. Ò ń ṣìkẹ́ ayé, o sì ń bomi rin ín,o mú kí ilẹ̀ jí kí ó sì lẹ́tù lójú;o mú kí omi kún inú odò ìwọ Ọlọrun,o mú kí ọkà hù lórí ilẹ̀;nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni o ṣe ṣètò rẹ̀. Orin Ìyìn ati Ọpẹ́. Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun. Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti dán wa wò;o ti dán wa wò bíi fadaka tí a dà ninu iná. O jẹ́ kí á bọ́ sinu àwọ̀n;o sì di ẹrù wúwo lé wa lórí. O jẹ́ kí àwọn eniyan máa gùn wá lórí mọ́lẹ̀,a ti la iná ati omi kọjá;sibẹsibẹ o mú wa wá sí ibi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú. N óo wá sinu ilé rẹ pẹlu ọrẹ ẹbọ sísun;n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ. Ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́,tí mo sì fi ẹnu mi sọ nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú. N óo fi ẹran àbọ́pa rú ẹbọ sísun sí ọ,èéfín ẹbọ àgbò yóo rú sókè ọ̀run,n óo fi akọ mààlúù ati òbúkọ rúbọ. Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọrun,n óo sì ròyìn ohun tí ó ṣe fún mi. Mo ké pè é,mo sì kọrin yìn ín. Bí mo bá gba ẹ̀ṣẹ̀ láyè ní ọkàn mi,OLUWA ìbá tí gbọ́ tèmi. Ṣugbọn nítòótọ́, Ọlọrun ti gbọ́;ó sì ti dáhùn adura mi. Ẹ kọ orin ògo yin orúkọ rẹ̀;ẹ yìn ín, ẹ fògo fún un! Ìyìn ni fún Ọlọrun,nítorí pé kò kọ adura mi;kò sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ kúrò lórí mi. Ẹ sọ fún Ọlọrun pé,“Iṣẹ́ rẹ bani lẹ́rù pupọ,agbára rẹ pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́,tí àwọn ọ̀tá rẹ fi ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ. Gbogbo ayé ní ń sìn ọ́;wọ́n ń kọ orin ìyìn fún ọ,wọ́n ń kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Ẹ wá wo ohun tí Ọlọrun ṣe,iṣẹ́ tí ó ń ṣe láàrin ọmọ eniyan bani lẹ́rù. Ó sọ òkun di ìyàngbẹ ilẹ̀,àwọn eniyan fi ẹsẹ̀ rìn kọjá láàrin odò.Inú wa dùn níbẹ̀ nítorí ohun tí ó ṣe. Nípa agbára rẹ̀ ó ń jọba títí lae.Ó ń ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè lójú mejeeji,kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má gbéraga sí i. Ẹ yin Ọlọrun wa, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ìró ìyìn rẹ̀; ẹni tí ó dá wa sí tí a fi wà láàyè,tí kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀. Orin Ọpẹ́. Kí Ọlọrun óo ṣàánú wa, kí ó bukun wa;kí ojú rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí wa lára; kí gbogbo ayé lè mọ ọ̀nà rẹ̀;kí gbogbo orílẹ̀-èdè sì mọ ìgbàlà rẹ̀. Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun;jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́! Kí inú àwọn orílẹ̀-èdè ó dùn,kí wọn ó máa kọrin ayọ̀,nítorí pé ò ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan láìṣe ojuṣaaju;o sì ń tọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé. Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun;jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́! Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀ ìkórè jáde;Ọlọrun, àní Ọlọrun wa, bukun wa. Ọlọrun bukun wa,kí gbogbo ayé máa bẹ̀rù rẹ̀. Orin ìṣẹ́gun ti Orílẹ̀-Èdè. Kí Ọlọrun dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ tú ká.Kí àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ sá níwájú rẹ̀. Àwọn eniyan rẹ rí ibùgbé lórí rẹ̀;Ọlọrun, ninu oore ọwọ́ rẹ, o pèsè fún àwọn aláìní. OLUWA fọhùn,ogunlọ́gọ̀ sì ni àwọn tí ó kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀. Gbogbo àwọn ọba ni ó sá tàwọn tọmọ ogun wọn;àwọn obinrin tí ó wà nílé, ati àwọn tí ó wà ní ibùjẹ ẹran rí ìkógun pín:fadaka ni wọ́n yọ́ bo apá ère àdàbà;wúrà dídán sì ni wọ́n yọ́ bo ìyẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Olodumare tú àwọn ọba ká,ní òkè Salimoni, yìnyín bọ́. Áà! Òkè Baṣani, òkè ńlá;Áà! Òkè Baṣani, òkè olórí pupọ. Ẹ̀yin òkè olórí pupọ,kí ló dé tí ẹ̀ ń fi ìlara wo òkè tí Ọlọrun fẹ́ràn láti máa gbé,ibi tí OLUWA yóo máa gbé títí lae? OLUWA sọ̀kalẹ̀ láti òkè Sinai sí ibi mímọ́ rẹ̀pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun kẹ̀kẹ́ ogun,ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun. Ó gun òkè gíga,ó kó àwọn eniyan nígbèkùn;ó gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn eniyan,ati lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ pàápàá.OLUWA Ọlọrun yóo máa gbébẹ̀. Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun ìgbàlà wa,tí ń bá wa gbé ẹrù wa lojoojumọ. Bí èéfín tií pòórá,bẹ́ẹ̀ ni kí wọn parẹ́;bí ìda tií yọ́ níwájú iná,bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn eniyan burúkú parun níwájú Ọlọrun. Ọlọrun tí ń gbani là ni Ọlọrun wa;OLUWA Ọlọrun ni ń yọni lọ́wọ́ ikú. Dájúdájú, OLUWA yóo fọ́ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀;yóo fọ́ àtàrí àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀. OLUWA ní,“N óo kó wọn pada láti Baṣani,n óo kó wọn pada láti inú ibú omi òkun, kí ẹ lè fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá yín,kí àwọn ajá yín lè lá ẹ̀jẹ̀ wọn bí ó ti wù wọ́n.” A ti rí ọ, Ọlọrun, bí o tí ń yan lọ,pẹlu ọ̀wọ́ èrò tí ń tẹ̀lé ọ lẹ́yìn.Ẹ wo Ọlọrun mi, ọba mi,bí ó ti ń yan wọ ibi mímọ́ rẹ̀, àwọn akọrin níwájú,àwọn onílù lẹ́yìn,àwọn ọmọbinrin tí ń lu samba láàrin. “Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọrun ninu àwùjọ eniyan,ẹ̀yin ìran Israẹli, ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA.” Ẹ wo Bẹnjamini tí ó kéré jù níwájú,ẹ wo ogunlọ́gọ̀ àwọn ìjòyè Juda,ẹ wo àwọn ìjòyè Sebuluni ati ti Nafutali. Fi agbára rẹ hàn, Ọlọrun,fi agbára tí o ti fi jà fún wa hàn. Nítorí Tẹmpili rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu,àwọn ọba yóo gbé ẹ̀bùn wá fún ọ. Ṣugbọn kí inú àwọn olódodo máa dùn,kí wọn máa yọ̀ níwájú Ọlọrun;kí wọn máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Bá àwọn ẹranko ẹ̀dá tí ń gbé inú èèsún ní Ijipti wí;àwọn akọ mààlúù, láàrin agbo ẹran àwọn orílẹ̀-èdè.Tẹ àwọn tí ó fẹ́ràn owó mọ́lẹ̀;fọ́n àwọn orílẹ̀-èdè tí ó fẹ́ràn ogun ká. Jẹ́ kí àwọn ikọ̀ wá láti Ijipti,kí àwọn ará Kuṣi tẹ́wọ́ adura sí Ọlọrun. Ẹ kọ orin sí Ọlọrun ẹ̀yin ìjọba ayé;ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA. Ẹni tí ń gun awọsanma lẹ́ṣin, àní awọsanma àtayébáyé;ẹ gbọ́ bí ó ṣe ń sán ààrá, ẹ gbọ́ ohùn alágbára. Ẹ bu ọlá fún Ọlọrun,ẹni tí ògo rẹ̀ wà lórí Israẹli;tí agbára rẹ̀ sì hàn lójú ọ̀run. Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni Ọlọrun ní ibi mímọ́ rẹ̀,Ọlọrun Israẹli;òun ni ó ń fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ọlá ati agbára.Ìyìn ni fún Ọlọrun! Ẹ kọrin sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ̀,ẹ pòkìkí ẹni tí ń gun ìkùukùu lẹ́ṣin.OLUWA ni orúkọ rẹ̀;ẹ máa yọ̀ níwájú rẹ̀. Baba àwọn aláìníbaba ati olùgbèjà àwọn opó ni Ọlọrun,ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́. Ọlọrun, olùpèsè ibùjókòó fún àlejò tí ó nìkan wà;ẹni tí ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra,ṣugbọn ó sì fi àwọn ọlọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ninu ilẹ̀ gbígbẹ. Ọlọrun, nígbà tí ò ń jáde lọ níwájú àwọn eniyan rẹ,nígbà tí ò ń yan la aṣálẹ̀ já, ilẹ̀ mì tìtì, ọ̀run pàápàá rọ òjò,níwájú Ọlọrun, Ọlọrun Sinai,àní, níwájú Ọlọrun Israẹli. Ọlọrun, ọpọlọpọ ni òjò tí o rọ̀ sílẹ̀;o sì mú ilẹ̀ ìní rẹ tí ó ti gbẹ pada bọ̀ sípò. Igbe fún Ìrànlọ́wọ́. Gbà mí, Ọlọrun,nítorí omi ti mù mí dé ọrùn. Nígbà tí mo fi omijé gbààwẹ̀,ó di ẹ̀gàn fún mi. Nígbà tí mò ń wọ aṣọ ọ̀fọ̀,mo di ẹni àmúpòwe. Èmi ni àwọn tí ń jókòó lẹ́nu ibodèfi ń ṣe ọ̀rọ̀ sọ;àwọn ọ̀mùtí sì ń fi mí ṣe orin kọ. Ṣugbọn ní tèmi, OLUWA, ìwọ ni mò ń gbadura síní àkókò tí ó bá yẹ, Ọlọrun,ninu ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,ninu agbára ìgbàlà rẹ, Ọlọrun dá mi lóhùn. Yọ mí ninu irà yìí, má jẹ́ kí n rì,gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Má jẹ́ kí ìgbì omi bò mí mọ́lẹ̀,kí ibú omi má gbé mi mì,kí isà òkú má sì padé mọ́ mi. Dá mi lóhùn, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹtí kì í yẹ̀ dára;fojú rere wò mí, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ àánú rẹ. Má ṣe fi ojú pamọ́ fún èmi, iranṣẹ rẹ,nítorí tí mo wà ninu ìdààmú,yára dá mi lóhùn. Sún mọ́ mi, rà mí pada,kí o sì tú mi sílẹ̀ nítorí àwọn ọ̀tá mi! O mọ ẹ̀gàn mi,o mọ ìtìjú ati àbùkù mi;o sì mọ gbogbo àwọn ọ̀tá mi. Mo ti rì sinu irà jíjìn,níbi tí kò ti sí ohun ìfẹsẹ̀tẹ̀;mo ti bọ́ sinu ibú,omi sì ti bò mí mọ́lẹ̀. Ẹ̀gàn ti mú kí inú mi bàjẹ́,tóbẹ́ẹ̀ tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sìmò ń retí àánú ṣugbọn kò sí;mò ń retí olùtùnú, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan. Iwọ ni wọ́n sọ di oúnjẹ fún mi,nígbà tí òùngbẹ sì ń gbẹ mí,ọtí kíkan ni wọ́n fún mi mu. Jẹ́ kí tabili oúnjẹ tí wọ́n tẹ́ fún arawọn di ẹ̀bìtì fún wọn;kí àsè ẹbọ wọn sì di tàkúté. Jẹ́ kí ojú wọn ṣú,kí wọn má lè ríran;kí gbogbo ara wọn sì máa gbọ̀n rìrì. Rọ òjò ibinu rẹ lé wọn lórí,kí o sì jẹ́ kí wọ́n rí gbígbóná ibinu rẹ. Kí ibùdó wọn ó di ahoro,kí ẹnikẹ́ni má sì gbé inú àgọ́ wọn. Nítorí ẹni tí o ti kọlù ni wọ́n tún gbógun tì;ẹni tí o ti ṣá lọ́gbẹ́ ni wọ́n sì tún ń pọ́n lójú. Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;má sì jẹ́ kí wọ́n rí ìdáláre lọ́dọ̀ rẹ. Pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè;kí á má sì kọ orúkọ wọn mọ́ ti àwọn olódodo. Ojú ń pọ́n mi, mo sì ń jẹ̀rora;Ọlọrun, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè! Mo sọkún títí àárẹ̀ mú mi,ọ̀nà ọ̀fun mi gbẹ,ojú mi sì di bàìbàì,níbi tí mo ti dúró, tí mò ń wo ojú ìwọ Ọlọrun mi. Èmi ó fi orin yin orúkọ Ọlọrun;n óo fi ọpẹ́ gbé e ga. Èyí yóo tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn ju akọ mààlúù lọ,àní, akọ mààlúù tòun tìwo ati pátákò rẹ̀. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo rí i,inú wọn yóo dùn;ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín sọjí. Nítorí OLUWA a máa gbọ́ ti àwọn aláìní,kì í sìí kẹ́gàn àwọn eniyan rẹ̀ tí ó wà ní ìgbèkùn. Jẹ́ kí ọ̀run ati ayé kí ó yìn ín,òkun ati gbogbo ohun tí ó ń rìn káàkiri ninu wọn. Nítorí Ọlọrun yóo gba Sioni là;yóo sì tún àwọn ìlú Juda kọ́;àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo máa gbé inú rẹ̀,yóo sì di tiwọn. Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo jogún rẹ̀;àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ̀ yóo sì máa gbé inú rẹ̀. Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí pọ̀,wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ.Àwọn tí ó fẹ́ pa mí run lágbára.Àwọn ọ̀tá mi ń parọ́ mọ́ mi,àwọn nǹkan tí n kò jíni wọ́n ní kí n fi dandan dá pada. Ọlọrun, o mọ ìwà òmùgọ̀ mi,àwọn àṣìṣe mi kò sì fara pamọ́ fún ọ. Má tìtorí tèmi dójúti àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ,OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,má sì tìtorí mi sọ àwọn tí ń wá ọ di ẹni àbùkù,Ọlọrun Israẹli. Nítorí tìrẹ ni mo ṣe di ẹni ẹ̀gàn,tí ìtìjú sì bò mí. Mo ti di àlejò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi,mo sì di àjèjì lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ìyá mi. Nítorí pé ìtara ilé rẹ ni ó jẹ mí lógún,ìwọ̀sí àwọn tí ó ń pẹ̀gàn rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀. Ọlọrun Onídàájọ́ Òdodo. OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo sá di;gbà mí là, kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi. Ọlọrun ni aláàbò mi,òun níí gba àwọn ọlọ́kàn mímọ́ là. Onídàájọ́ òdodo ni Ọlọrun,a sì máa bínú sí àwọn aṣebi lojoojumọ. Bí wọn kò bá yipada, Ọlọrun yóo pọ́n idà rẹ̀;ó ti tẹ ọrun rẹ̀, ó sì ti fi ọfà lé e. Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀,ó sì ti tọ́jú ọfà iná. Wò ó, eniyan burúkú lóyún ibi, ó lóyún ìkà, ó sì bí èké. Ó gbẹ́ kòtò,ó sì jìn sinu kòtò tí ó gbẹ́. Ìkà rẹ̀ pada sórí ara rẹ̀,àní ìwà ipá rẹ̀ sì já lù ú ní àtàrí. N óo fi ọpẹ́ tí ó yẹ fún OLUWA nítorí òdodo rẹ̀,n óo fi orin ìyìn kí OLUWA, Ọ̀gá Ògo. Kí wọn má baà fà mí ya bíi kinniun,kí wọn máa wọ́ mi lọ láìsí ẹni tí ó lè gbà mí sílẹ̀. OLUWA, Ọlọrun mi, bí mo bá ṣe nǹkan yìí,bí iṣẹ́ ibi bá ń bẹ lọ́wọ́ mi, bí mo bá fi ibi san án fún olóore,tabi tí mo bá kó ọ̀tá mi lẹ́rú láìnídìí, jẹ́ kí ọ̀tá ó lé mi bá,kí ó tẹ̀ mí pa,kí ó sì bo òkú mi mọ́ ilẹ̀ẹ́lẹ̀. OLUWA, fi ibinu dìde!Gbéra, kí o bá àwọn ọ̀tá mi jà ninu ìrúnú wọn;jí gìrì, Ọlọrun mi; ìwọ ni o ti fi ìlànà òdodo lélẹ̀. Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ó rọ̀gbà yí ọ ká,kí o sì máa jọba lé wọn lórí láti òkè wá. OLUWA ló ń ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé;dá mi láre, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi ati ìwà pípé mi. Ìwọ Ọlọrun Olódodo, tí o mọ èrò ati ìfẹ́ inú eniyan,fi òpin sí ìwà ibi àwọn eniyan burúkú,kí o sì fi ìdí àwọn olódodo múlẹ̀. Adura Ìrànlọ́wọ́. Ọlọrun, dákun, gbà mí,yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́. Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọn fẹ́ gba ẹ̀mí mikí ìdàrúdàpọ̀ bá wọn;jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,kí wọn sì tẹ́. Jẹ́ kí jìnnìjìnnì boàwọn tí ń yọ̀ mí, tí ń ṣe jàgínní mi;kí wọn sì gba èrè ìtìjú. Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀ nítorí rẹ,kí inú wọn sì máa dùn,kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé,“Ọlọrun tóbi!” Ṣugbọn ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí,yára wá sọ́dọ̀ mi, Ọlọrun!Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi ati olùgbàlà mi,má pẹ́ OLÚWA. Adura Àgbàlagbà kan. OLUWA, ìwọ ni mo sá di;má jẹ́ kí ojú ó tì mí laelae! Nítorí pé àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi,àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi ti pàmọ̀ pọ̀, wọ́n ní, “Ọlọrun ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;ẹ lé e, ẹ mú un;nítorí kò sí ẹni tí yóo gbà á sílẹ̀ mọ́.” Ọlọrun, má jìnnà sí mi;yára, Ọlọrun mi, ràn mí lọ́wọ́! Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn alátakò mi, kí wọn parun;kí ẹ̀gàn ati ìtìjú bo àwọn tí ń wá ìpalára mi. Ní tèmi, èmi ó máa ní ìrètí nígbà gbogbo,n óo sì túbọ̀ máa yìn ọ́. N óo máa ṣírò iṣẹ́ rere rẹ,n óo máa ròyìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ̀sán-tòru,nítorí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè mọ iye wọn. N óo wá ninu agbára OLUWA Ọlọrun,n óo máa kéde iṣẹ́ òdodo rẹ, àní, iṣẹ́ òdodo tìrẹ nìkan. Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi,títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ, Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi,Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀,títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ,àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀. Ọlọrun, iṣẹ́ òdodo rẹ kan ojú ọ̀run,ìwọ tí o ṣe nǹkan ńlá,Ọlọrun, ta ni ó dàbí rẹ? Gbà mí, kí o sì yọ mí nítorí òdodo rẹ;tẹ́tí sí mi kí o sì gbà mí là! O ti jẹ́ kí n rí ọpọlọpọ ìpọ́njú ńlá,ṣugbọn óo tún mú ìgbé ayé mi pada bọ̀ sípò;óo tún ti gbé mi dìde láti inú isà òkú. O óo fi kún ọlá mi,o óo sì tún tù mí ninu. Èmi náà óo máa fi hapu yìn ọ́,nítorí òtítọ́ rẹ, Ọlọrun mi;n óo máa fi ohun èlò orin yìn ọ́,ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli. N óo máa kígbe fún ayọ̀,nígbà tí mo bá ń kọ orin ìyìn sí ọ;ẹ̀mí mi tí o ti kó yọ, yóo ké igbe ayọ̀. Ẹnu mi yóo ròyìn iṣẹ́ rẹ tọ̀sán-tòru,nítorí a ti ṣẹgun àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,a sì ti dójú tì wọ́n. Máa ṣe àpáta ààbò fún mi,jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí,nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi. Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,àwọn alaiṣootọ ati ìkà. Nítorí ìwọ OLUWA, ni ìrètí mi,OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà èwe mi. Ìwọ ni mo gbára lé láti inú oyún;ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi.Ìwọ ni n óo máa yìn nígbà gbogbo. Mo di ẹni àmúpòwe fún ọpọlọpọ eniyan,ṣugbọn ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára. Ẹnu mi kún fún ìyìn rẹ,ó kún fún ògo rẹ tọ̀sán-tòru. Má ta mí nù ní ìgbà ogbó mi;má sì gbàgbé mi nígbà tí n kò bá lágbára mọ́. Adura Ọba. Ọlọrun, gbé ìlànà òtítọ́ rẹ lé ọba lọ́wọ́;kọ́ ọmọ ọba ní ọ̀nà òdodo rẹ. Àwọn ọba Taṣiṣi ati àwọn ọba erékùṣù gbogboyóo máa san ìṣákọ́lẹ̀ fún un;àwọn ọba Ṣeba ati ti Seba yóo máa mú ẹ̀bùn wá. Gbogbo àwọn ọba yóo máa wólẹ̀ fún un;gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì máa sìn ín. Nítorí pé a máa gba talaka tí ó bá ké pè é sílẹ̀;a sì máa gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀,ati àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. A máa ṣíjú àánú wo àwọn aláìní ati talaka,a sì máa gba àwọn talaka sílẹ̀. A máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn aninilára ati oníwà ipá,ẹ̀mí wọn sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ yóo gùn,a óo máa fi wúrà Ṣeba ta á lọ́rẹ,a óo máa gbadura fún un nígbà gbogbo;a óo sì máa súre fún un tọ̀sán-tòru. Ọkà yóo pọ̀ lóko,yóo máa mì lẹ̀gbẹ̀ lórí òkè;èso rẹ̀ yóo dàbí ti Lẹbanoni,eniyan yóo pọ̀ ní ìlú,bíi koríko ninu pápá. Orúkọ ọba óo wà títí lae,òkìkí rẹ̀ óo sì máa kàn níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn;àwọn eniyan óo máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún ara wọn,gbogbo orílẹ̀-èdè óo sì máa pè é ní olóríire. Ẹni-ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli,ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu tí ẹlòmíràn kò lè ṣe. Ẹni ìyìn títí lae ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ lókìkí,kí òkìkí rẹ̀ gba ayé kan!Amin! Amin. Kí ó lè máa fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ,kí ó sì máa dá ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́; Níbi tí adura Dafidi ọmọ Jese parí sí nìyí. kí àwọn eniyan tí ó gbé orí òkè ńlá lè rí alaafia,kí nǹkan sì dára fún àwọn tí ń gbé orí òkè kéékèèké. Jẹ́ kí ó máa gbèjà àwọn eniyan tí ìyà ń jẹ;kí ó máa gba àwọn ọmọ talaka sílẹ̀;kí ó sì rún àwọn aninilára wómúwómú. Ọlọrun, jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ máa bẹ̀rù rẹ láti ìran dé ìran,níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn, tí òṣùpá sì ń yọ. Jẹ́ kí ọba ó dàbí òjò tí ó rọ̀ sórí koríko tí a ti géàní, bí ọ̀wààrà òjò tí ń rin ilẹ̀. Kí ìwà rere ó gbèrú ní ìgbà tirẹ̀;kí alaafia ó gbilẹ̀ títítí òṣùpá kò fi ní yọ mọ́. Kí ìjọba rẹ̀ ó lọ láti òkun dé òkun,ati láti odò ńlá títí dé òpin ayé. Àwọn tí ń gbé aṣálẹ̀ yóo máa foríbalẹ̀ fún un;àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo sì máa fi ẹnu gbo ilẹ̀ níwájú rẹ̀. Ìdájọ́ Òdodo Ọlọrun. Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli,ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́. Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn,wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe. Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀?Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?” Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí;ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i. Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́,tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi. Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu;láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà. Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,”n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà. Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi,mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni. Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ,ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn. Nítòótọ́ ibi tí ń yọ̀ ni ó gbé wọn lé,ó sì mú kí wọn ṣubú sinu ìparun. Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán,tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata. Ṣugbọn, ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ yọ̀ ṣubú,ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tàsé. Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí.OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá. Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́,tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi, mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye,mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ. Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ;o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà;lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo. Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ?Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ. Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi,ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi,ati ìpín mi títí lae. Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé,o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run. Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun;mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi,kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ. Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraganígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú. Wọn kì í jẹ ìrora kankan,ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀. Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn;ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn. Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà,wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ. Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò;èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀. Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara;wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀. Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun;wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé. Ranti Wa, OLUWA. Ọlọrun, kí ló dé tí o fi ta wá nù títí ayé?Kí ló dé tí inú rẹ fi ń ru sí àwa aguntan pápá rẹ? Yóo ti pẹ́ tó, Ọlọrun, tí ọ̀tá yóo máa fi ọ́ ṣẹ̀fẹ̀?Ṣé títí ayé ni ọ̀tá yóo máa gan orúkọ rẹ ni? Kí ló dé tí o ò ṣe nǹkankan?Kí ló dé tí o káwọ́ gbera? Ọlọrun, ìwọ ṣá ni ọba wa láti ìbẹ̀rẹ̀ wá;ìwọ ni o máa ń gbà wá là láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè. Ìwọ ni o fi agbára rẹ pín òkun níyà;o fọ́ orí àwọn ẹranko ńlá inú omi. Ìwọ ni o fọ́ orí Lefiatani túútúú;o sì fi òkú rẹ̀ ṣe ìjẹ fún àwọn ẹranko inú aṣálẹ̀. Ìwọ ni o fọ́ àpáta tí omi tú jáde, tí odò sì ń ṣàn,ìwọ ni o sọ odò tí ń ṣàn di ilẹ̀ gbígbẹ. Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ náà sì ni òru,ìwọ ni o gbé òṣùpá ati oòrùn ró. Ìwọ ni o pa gbogbo ààlà ilẹ̀ ayé;ìwọ ni o dá ìgbà òjò ati ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. OLUWA, ranti pé àwọn ọ̀tá ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́;àwọn òmùgọ̀ eniyan sì ń fi orúkọ rẹ ṣe ẹlẹ́yà. Má fi ẹ̀mí àwa àdàbà rẹ lé àwọn ẹranko lọ́wọ́;má sì gbàgbé àwa eniyan rẹ tí ìyà ń jẹ títí lae. Ranti ìjọ eniyan rẹ tí o ti rà ní ìgbà àtijọ́,àwọn ẹ̀yà tí o rà pada láti fi ṣe ogún tìrẹ;ranti òkè Sioni níbi tí o ti ń gbé rí. Ranti majẹmu rẹ;nítorí pé gbogbo kọ̀rọ̀ ilẹ̀ wa kún fún ìwà ipá. Má jẹ́ kí ojú ti àwọn tí à ń pọ́n lójú;jẹ́ kí àwọn tí ìyà ń jẹ ati àwọn aláìní máa yin orúkọ rẹ. Dìde Ọlọrun, gbèjà ara rẹ;ranti bí àwọn òmùgọ̀ eniyan tí ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru. Má gbàgbé ariwo àwọn ọ̀tá rẹ;àní, igbe àwọn tí ó gbógun tì ọ́, tí wọn ń ké láìdá ẹnu dúró. Rìn káàkiri kí o wo bí gbogbo ilẹ̀ ti di ahoro,wo bí ọ̀tá ti ba gbogbo nǹkan jẹ́ ninu ibi mímọ́ rẹ. Àwọn ọ̀tá rẹ bú ramúramù ninu ilé ìsìn rẹ;wọ́n ta àsíá wọn gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣẹ́gun. Wọ́n dàbí ẹni tí ó gbé àáké sókè,tí ó fi gé igi ìṣẹ́pẹ́. Gbogbo pákó tí a fi dárà sí ara ògirini wọ́n fi àáké ati òòlù fọ́. Wọ́n jó ibi mímọ́ rẹ kanlẹ̀;wọ́n sì ba ilé tí a ti ń pe orúkọ rẹ jẹ́. Wọ́n pinnu lọ́kàn wọn pé, “A óo bá wọn kanlẹ̀ patapata.”Wọ́n dáná sun gbogbo ilé ìsìn Ọlọrun tí ó wà ní ilẹ̀ náà. A kò rí àsíá wa mọ́,kò sí wolii mọ́;kò sì sí ẹnìkan ninu wa tí ó mọ bí ìṣòro wa yóo ti pẹ́ tó. Ọlọrun Onídàájọ́. A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun; a dúpẹ́.À ń kéde orúkọ rẹ,a sì ń ròyìn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe. Ọlọrun yóo gba gbogbo agbára ọwọ́ àwọn eniyan burúkú kúrò;ṣugbọn yóo fi agbára kún agbára fún àwọn olódodo. OLUWA ní, “Nígbà tí àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ bá tó,n óo ṣe ìdájọ́ pẹlu àìṣojúṣàájú. Nígbà tí ayé bá ń mì síhìn-ín sọ́hùn-ún,ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀;èmi a mú kí òpó rẹ̀ dúró wámúwámú. Èmi a sọ fún àwọn tí ń fọ́nnu pé, ‘Ẹ yé fọ́nnu’;èmi a sì sọ fún àwọn eniyan burúkú pé, ‘Ẹ yé ṣe ìgbéraga.’ Ẹ má halẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,ẹ má sì gbéraga.” Nítorí pé kì í ṣe láti ìlà oòrùn,tabi láti ìwọ̀ oòrùn,bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe apá gúsù tabi àríwá ni ìgbéga tií wá. Ọlọrun níí dájọ́ bí ó ti wù ú:á rẹ ẹnìkan sílẹ̀, á sì gbé ẹlòmíràn ga. Ife kan wà ní ọwọ́ OLUWA,Ibinu Oluwa ló kún inú rẹ̀,ó ń ru bí ọtí àní bí ọtí tí a ti lú,yóo ṣẹ́ ninu rẹ̀;gbogbo àwọn eniyan burúkú ilẹ̀ ayé ni yóo sì mu ún,wọn óo mu ún tán patapata tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn èmi óo máa yọ̀ títí lae,n óo kọ orin ìyìn sí Ọlọrun Jakọbu. Ọlọrun Ajàṣẹ́gun. Àwọn ará Juda mọ Ọlọrun,orúkọ rẹ̀ sì lọ́wọ̀ ní Israẹli. Dájúdájú ibinu eniyan yóo pada di ìyìn fún ọ;àwọn tí wọ́n bá sì bọ́ lọ́wọ́ ibinu rẹyóo ṣe àjọ̀dún rẹ. Jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì mú un ṣẹ,kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wáfún ẹni tí ó yẹ kí á bẹ̀rù. Ẹni tí ń gba ẹ̀mí àwọn ìjòyè,tí ó ń ṣe ẹ̀rù ba àwọn ọba ayé. Ilé rẹ̀ wà ní Salẹmu,ibùgbé rẹ̀ wà ní Sioni. Níbẹ̀ ni ó ti ṣẹ́ ọfà ọ̀tá tí ń rọ̀jò,ati apata, ati idà, ati àwọn ohun ìjà ogun. Ológo ni ọ́, ọlá rẹ sì pọ̀,ó ju ti àwọn òkè tí ó kún fún ẹran lọ. A gba ìkógun lọ́wọ́ àwọn akikanju,wọ́n sun oorun àsùn-ùn-jí;àwọn alágbára kò sì le gbé ọwọ́ láti jà. Nípa ìbáwí rẹ, Ọlọrun Jakọbu,ati ẹṣin, ati ẹni tó gun ẹṣin,gbogbo wọn ló ṣubú lulẹ̀, tí wọn kò sì lè mira. Ṣugbọn ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni ọ́!Ta ló tó dúró níwájú rẹtí ibinu rẹ bá dé? Láti ọ̀run wá ni o ti ń ṣe ìdájọ́,ẹ̀rù ba ayé, ayé sì dúró jẹ́ẹ́; nígbà tí Ọlọrun dìde láti gbé ìdájọ́ kalẹ̀,láti gba gbogbo àwọn tí à ń nilára láyé sílẹ̀. Ìtùnú ní Àkókò Ìpọ́njú. Mo ké pe Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́,mo kígbe pe Ọlọrun kí ó lè gbọ́ tèmi. Nígbà náà ni mo wí pé, “Ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́ ni péỌ̀gá Ògo kò jẹ́wọ́ agbára mọ́.” N óo ranti àwọn iṣẹ́ OLUWA,àní, n óo ranti àwọn iṣẹ́ ìyanu ìgbàanì. N óo máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ;n óo sì máa ronú lórí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe. Ọlọrun, mímọ́ ni ọ̀nà rẹ;oriṣa wo ni ó tó Ọlọrun wa? Ìwọ ni Ọlọrun tí ń ṣe ohun ìyanu;o ti fi agbára rẹ hàn láàrin àwọn eniyan. O ti fi agbára rẹ gba àwọn eniyan rẹ là;àní, àwọn ọmọ Jakọbu ati Josẹfu. Nígbà tí omi òkun rí ọ, Ọlọrun,àní, nígbà tí omi òkun fi ojú kàn ọ́,ẹ̀rù bà á;ibú omi sì wárìrì. Ìkùukùu da omi òjò sílẹ̀,ojú ọ̀run sán ààrá;mànàmáná ń kọ yẹ̀rì káàkiri. Ààrá ń sán kíkankíkan ní ojú ọ̀run,mànàmáná ń kọ yànràn, gbogbo ayé sì mọ́lẹ̀;ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì. Ọ̀nà rẹ wà lójú omi òkun,ipa ọ̀nà rẹ la omi òkun ńlá já;sibẹ ẹnìkan kò rí ipa ẹsẹ̀ rẹ. Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi, mo wá OLUWA;ní òru, mo tẹ́wọ́ adura láìkáàárẹ̀,ṣugbọn n kò rí ìtùnú. O kó àwọn eniyan rẹ jáde bí agbo ẹran,o fi Mose ati Aaroni ṣe olórí wọn. Mo ronú nípa Ọlọrun títí, mò ń kérora;mo ṣe àṣàrò títí, ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì. OLUWA, o ò jẹ́ kí n dijú wò ní gbogbo òrumo dààmú tóbẹ́ẹ̀ tí n kò le sọ̀rọ̀. Mo ranti ìgbà àtijọ́,mo ranti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Mo ronú jinlẹ̀ lóru,mo ṣe àṣàrò, mo yẹ ọkàn mi wò. Ṣé Ọlọrun yóo kọ̀ wá sílẹ̀ títí lae ni;àbí inú rẹ̀ kò tún ní dùn sí wa mọ́? Ṣé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ti pin títí lae ni;àbí ìlérí rẹ̀ ti dópin patapata? Ṣé Ọlọrun ti gbàgbé láti máa ṣoore ni;àbí ó ti fi ibinu pa ojú àánú rẹ̀ dé? Ọlọrun ati Àwọn Eniyan Rẹ̀. Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ dẹtí sí ẹ̀kọ́ mi;ẹ tẹ́tí si ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Wọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́,wọ́n kọ̀, wọn kò jẹ́ pa òfin rẹ̀ mọ́. Wọ́n gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe hàn wọ́n. Ní ìṣojú àwọn baba ńlá wọn, ó ṣe ohun ìyanu,ní ilẹ̀ Ijipti, ní oko Soani. Ó pín òkun níyà, ó jẹ́ kí wọ́n kọjá láàrin rẹ̀;ó sì mú kí omi nàró bí òpó ńlá. Ó fi ìkùukùu ṣe atọ́nà wọn ní ọ̀sán,ó fi ìmọ́lẹ̀ iná tọ́ wọn sọ́nà ní gbogbo òru. Ó la àpáta ni aṣálẹ̀,ó sì fún wọn ní omi mu lọpọlọpọ bí ẹni pé láti inú ibú. Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta;ó sì mú kí ó ṣàn bí odò. Sibẹsibẹ wọn ò dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá;wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo ninu aṣálẹ̀. Wọ́n dán Ọlọrun wò ninu ọkàn wọn,wọ́n ń wá oúnjẹ tí yóo tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn. Wọ́n sọ̀rọ̀ ìwọ̀sí sí Ọlọrun, wọ́n ní,“Ṣé Ọlọrun lè gbé oúnjẹ kalẹ̀ fún wa ninu aṣálẹ̀? N óo la ẹnu mi tòwe-tòwe;n óo fa ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àtijọ́ yọ, Lóòótọ́ ó lu òkúta tí omi fi tú jáde,tí odò sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn.Ṣé ó lè fún wa ní òkèlè pẹlu,àbí ó lè pèsè ẹran fún àwọn eniyan rẹ̀?” Nítorí náà nígbà tí OLUWA gbọ́,inú bí i;iná mọ́ ìdílé Jakọbu,inú OLUWA sì ru sí àwọn ọmọ Israẹli; nítorí pé wọn kò gba Ọlọrun gbọ́;wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé agbára ìgbàlà rẹ̀. Sibẹ ó pàṣẹ fún ìkùukùu lókè,ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀. Ó rọ òjò mana sílẹ̀fún wọn láti jẹ,ó sì fún wọn ní ọkà ọ̀run. Ọmọ eniyan jẹ lára oúnjẹ àwọn angẹli;Ọlọrun fún wọn ní oúnjẹ àjẹtẹ́rùn. Ó mú kí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn fẹ́ ní ojú ọ̀run,ó sì fi agbára rẹ̀ darí afẹ́fẹ́ ìhà gúsù; ó sì rọ̀jò ẹran sílẹ̀ fún wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀;àní, ẹyẹ abìyẹ́ bíi yanrìn etí òkun. Ó mú kí wọn bọ́ sílẹ̀ láàrin ibùdó;yíká gbogbo àgọ́ wọn, Àwọn eniyan náà jẹ, wọ́n sì yó;nítorí pé Ọlọrun fún wọn ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́. ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,ohun tí àwọn baba ńlá wa ti sọ fún wa. Ṣugbọn kí wọn tó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn,àní, nígbà tí wọn ṣì ń jẹun lọ́wọ́. Ọlọrun bínú sí wọn;ó pa àwọn tí ó lágbára jùlọ ninu wọn,ó sì lu àṣàyàn àwọn ọdọmọkunrin Israẹli pa. Sibẹsibẹ wọ́n tún dẹ́ṣẹ̀;pẹlu gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọn kò gbàgbọ́. Nítorí náà ó mú kí ọjọ́ ayé wọn pòórá bí afẹ́fẹ́;wọ́n sì lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìjayà. Nígbàkúùgbà tí ó bá ń pa wọ́n, wọn á wá a;wọn á ronupiwada, wọn á sì wá Ọlọrun tọkàntọkàn. Wọn á ranti pé Ọlọrun ni àpáta ààbò wọn,ati pé Ọ̀gá Ògo ni olùràpadà wọn. Ṣugbọn wọn kàn ń fi ẹnu wọn pọ́n ọn ni;irọ́ ni wọ́n sì ń pa fún un. Ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin lọ́dọ̀ rẹ̀;wọn kò sì pa majẹmu rẹ̀ mọ́. Sibẹ, nítorí pé aláàánú ni, ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n,kò sì pa wọ́n run;ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró,tí kò sì fi gbogbo ara bínú sí wọn. Ó ranti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,afẹ́fẹ́ lásán tí ń fẹ́ kọjá lọ, tí kò sì ní pada mọ́. A kò ní fi pamọ́ fún àwọn ọmọ wọn;a óo máa sọ ọ́ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn–iṣẹ́ ńlá OLUWA ati ìṣe akọni rẹ̀,ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe. Ìgbà mélòó ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ninu ijù,tí wọ́n sì bà á lọ́kàn jẹ́ ninu aṣálẹ̀! Wọ́n dán an wò léraléra,wọ́n sì mú Ẹni Mímọ́ Israẹli bínú. Wọn kò ranti agbára rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ranti ọjọ́ tí ó rà wọ́n pada lọ́wọ́ ọ̀tá; nígbà tí ó ṣe iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti,tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní oko Soani. Ó sọ omi odò wọn di ẹ̀jẹ̀,tí wọn kò fi lè mu omi wọn. Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin sí wọn tí ó jẹ wọ́n,ati ọ̀pọ̀lọ́ tí ó pa wọ́n run. Ó mú kí kòkòrò jẹ èso ilẹ̀ wọn;eṣú sì jẹ ohun ọ̀gbìn wọn. Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́;ó sì fi òjò dídì run igi Sikamore wọn. Ó fi yìnyín pa mààlúù wọn;ó sì sán ààrá pa agbo aguntan wọn. Ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ lé wọn lórí:ìrúnú, ìkannú, ati ìpọ́njú,wọ́n dàbí ikọ̀ ìparun. Ó fi ìlànà lélẹ̀ fún ìdílé Jakọbu;ó gbé òfin kalẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.Ó pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa,pé kí wọ́n fi kọ́ àwọn ọmọ wọn. Ó fi àyè gba ibinu rẹ̀;kò dá ẹ̀mí wọn sí,ó sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n. O kọlu gbogbo àkọ́bí wọn ní ilẹ̀ Ijipti,àní, gbogbo àrẹ̀mọ ninu àgọ́ àwọn ọmọ Hamu. Lẹ́yìn náà, ó kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde bí agbo ẹranó sì dà wọ́n láàrin aṣálẹ̀ bí agbo aguntan. Ó dà wọ́n lọ láìléwu, ẹ̀rù kò bà wọ́n;òkun sì bo àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀. Ó kó wọn wá sí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀,sí orí òkè tí ó ti fi agbára rẹ̀ gbà. Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde kí wọn ó tó dé ibẹ̀;ó pín ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn bí ohun ìní;ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli jókòó ninu àgọ́ wọn. Sibẹ, wọ́n dán Ọ̀gá Ògo wò, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí i;wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ̀. Wọ́n yipada, wọ́n sì hu ìwà ọ̀dàlẹ̀bíi ti àwọn baba ńlá wọn;wọn kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, wọ́n dàbí ọfà tí ó tẹ̀. Wọ́n fi ojúbọ àwọn oriṣa wọn bí i ninu;wọ́n sì fi ère wọn mú un jowú. Nígbà tí Ọlọrun gbọ́, inú bí i gidigidi;ó sì kọ Israẹli sílẹ̀ patapata. Kí àwọn ìran tí ń bọ̀ lè mọ̀ ọ́n,àní, àwọn ọmọ tí a kò tíì bí,kí àwọn náà ní ìgbà tiwọnlè sọ ọ́ fún àwọn ọmọ wọn. Ó kọ ibùgbé rẹ̀ ní Ṣilo sílẹ̀,àní, àgọ́ rẹ̀ láàrin ọmọ eniyan. Ó jẹ́ kí á gbé àmì agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn;ó sì fi ògo rẹ̀ lé ọ̀tá lọ́wọ́. Ó jẹ́ kí á fi idà pa àwọn eniyan rẹ̀;ó sì bínú gidigidi sí àwọn eniyan ìní rẹ̀. Iná run àwọn ọdọmọkunrin wọn;àwọn ọdọmọbinrin wọn kò sì rójú kọrin igbeyawo. Àwọn alufaa kú ikú ogun;àwọn opó wọn kò sì rójú sọkún. Lẹ́yìn náà, OLUWA dìde bí ẹni tají lójú oorun,bí ọkunrin alágbára tí ó mu ọtí yó tí ó ń kígbe. Ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ sẹ́yìn;ó dójú tì wọ́n títí ayé. Ó kọ àgọ́ àwọn ọmọ Josẹfu sílẹ̀;kò sì yan ẹ̀yà Efuraimu; ṣugbọn ó yan ẹ̀yà Juda,ó sì yan òkè Sioni tí ó fẹ́ràn. Níbẹ̀ ni ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀ tí ó ga bí ọ̀run sí,ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí ayé títí lae. Kí wọn lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun,kí wọn má gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,kí wọn sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́, Ó yan Dafidi iranṣẹ rẹ̀;ó sì mú un láti inú agbo ẹran. Ó mú un níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn aguntantí ó lọ́mọ lẹ́yìn,kí ó lè máa tọ́jú àwọn ọmọ Jakọbu, eniyan rẹ̀,àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan ìní rẹ̀. Ó tọ́jú wọn pẹlu òdodo,ó sì tọ́ wọn pẹlu ìmọ̀. kí wọn má dàbí àwọn baba ńlá wọn,ìran àwọn olóríkunkun ati ọlọ̀tẹ̀,àwọn tí ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin,tí ẹ̀mí wọn kò sì dúró gbọningbọnin ti Olodumare. Àwọn ọmọ Efuraimu kó ọrun, wọ́n kó ọfà,ṣugbọn wọ́n pẹ̀yìndà lọ́jọ́ ìjà. Adura Ìdáǹdè Orílẹ̀-Èdè. Ọlọrun, àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ti wọ inú ilẹ̀ ìní rẹ;wọ́n ti ba ilé mímọ́ rẹ jẹ́;wọ́n sì ti sọ Jerusalẹmu di ahoro. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi máa sọ pé,“Níbo ni Ọlọrun wọn wà?”Níṣojú wa, gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ tí a palára àwọn orílẹ̀-èdè! Jẹ́ kí ìkérora àwọn ìgbèkùn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ;gẹ́gẹ́ bí agbára ńlá rẹ,dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sí. OLUWA, san ẹ̀san ẹ̀gàn tí àwọn aládùúgbò wa gàn ọ́,san án fún wọn ní ìlọ́po meje, Nígbà náà, àwa eniyan rẹ,àní, àwa agbo aguntan pápá rẹ,yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae;a óo sì máa sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ láti ìran dé ìran. Wọ́n ti fi òkú àwọn iranṣẹ rẹfún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ;wọ́n sì ti sọ òkú àwọn eniyan mímọ́ rẹ di ìjẹfún àwọn ẹranko ìgbẹ́. Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ bí omi, káàkiri Jerusalẹmu;kò sì sí ẹni tí yóo gbé wọn sin. A ti di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa;àwọn tí ó yí wa ká ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́;wọ́n sì ń fi wá rẹ́rìn-ín. Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA?Ṣé títí ayé ni o óo máa bínú ni?Àbí owú rẹ yóo máa jó bí iná? Tú ibinu rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́,ati orí àwọn ìjọba tí kò sìn ọ́. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run;wọ́n sì ti sọ ibùgbé rẹ di ahoro. Má gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wa lára wa;yára, kí o ṣàánú wa,nítorí pé a ti rẹ̀ wá sílẹ̀ patapata. Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọrun Olùgbàlà wa,nítorí iyì orúkọ rẹ;gbà wá, sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,nítorí orúkọ rẹ. Ògo OLUWA ati Ipò Eniyan. OLUWA, Oluwa wa,orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé!Ìwọ ni o gbé ògo rẹ kalẹ̀ lókè ọ̀run. Àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ń kọrin ògo rẹ,wọ́n ti fi ìdí agbára rẹ múlẹ̀,nítorí àwọn tí ó kórìíra rẹ,kí á lè pa àwọn ọ̀tá ati olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́. Nígbà tí mo ṣe akiyesi ojú ọ̀run, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, tí o sọlọ́jọ̀– Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀?Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀? O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ sí ti ìwọ Ọlọrun,o sì ti fi ògo ati ọlá dé e ní adé. O mú un jọba lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,o sì fi gbogbo nǹkan sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀: àwọn aguntan, ati àwọn mààlúù, ati gbogbo ẹranko ninu igbó; àwọn ẹyẹ ojú ọrun, àwọn ẹja inú òkun,ati gbogbo nǹkan tí ó ń lúwẹ̀ẹ́ ninu òkun. OLUWA, Oluwa wa,orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé! Fi Ojurere Wò Wá. Dẹtí sílẹ̀, ìwọ olùṣọ́-aguntan Israẹli,Ìwọ tí ò ń tọ́jú àwọn ọmọ Josẹfu bí agbo ẹran.Ìwọ tí o gúnwà láàrin àwọn kerubu, yọ bí ọjọ́ Òjìji rẹ̀ bo àwọn òkè mọ́lẹ̀,ẹ̀ka rẹ sì bo àwọn igi kedari ńláńlá; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tàn kálẹ̀ títí kan òkun,àwọn èèhù rẹ̀ sì kan odò ńlá. Kí ló dé tí o fi wó ògiri ọgbà rẹ̀,tí gbogbo àwọn tí ń kọjá lọsì fi ń ká èso rẹ̀? Àwọn ìmàdò inú ìgbẹ́ ń jẹ ẹ́ ní àjẹrun,gbogbo àwọn nǹkan tí ń káàkiri ninu oko sì ń jẹ ẹ́. Jọ̀wọ́ tún yipada, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun!Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì wò ó;kí o sì tọ́jú ìtàkùn àjàrà yìí, ohun ọ̀gbìn tí o fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbìn,àní, ọ̀dọ́ igi tí o fi ọwọ́ ara rẹ tọ́jú. Àwọn ọ̀tá ti dáná sun ún, wọ́n ti gé e lulẹ̀;fi ojú burúkú wò wọ́n, kí wọ́n ṣègbé! Ṣugbọn di ẹni tí o fúnra rẹ yàn mú,àní, ọmọ eniyan, tí o fúnra rẹ sọ di alágbára. Ṣe bẹ́ẹ̀, a kò sì ní pada lẹ́yìn rẹ;dá wa sí, a ó sì máa sìn ọ́! Mú wa bọ̀ sípò, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun!Fi ojurere wò wá, kí á lè là! níwájú Efuraimu ati Bẹnjamini ati Manase.Sọ agbára rẹ jí,kí o sì wá gbà wá là. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun;fi ojurere wò wá,kí á le gbà wá là. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa bínú sí aduraàwọn eniyan rẹ? O ti fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ,o sì ti fún wọn ní omijé mu ní àmuyó. O ti mú kí àwọn aládùúgbò wa máa jìjàdù lórí wa;àwọn ọ̀tá wa sì ń fi wá rẹ́rìn-ín láàrin ara wọn. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun;fi ojurere wò wá,kí á lè là. O mú ìtàkùn àjàrà kan jáde láti Ijipti;o lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbìn ín. O ro ilẹ̀ fún un;ó ta gbòǹgbò wọlẹ̀, igi rẹ̀ sì gbilẹ̀. Orin fún Àkókò Àsè. Ẹ kọ orin sókè sí Ọlọrun, agbára wa;ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun Jakọbu. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín,tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti.Ẹ ya ẹnu yín dáradára, n óo sì bọ yín ní àbọ́yó. “Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu,Israẹli kò sì gba tèmi. Nítorí náà mo fi wọ́n sílẹ̀ sinu agídí ọkàn wọn,kí wọn máa ṣe ohun tó wù wọ́n. Àwọn eniyan mi ìbá jẹ́ gbọ́ tèmi,àní Israẹli ìbá jẹ́ máa rìn ní ọ̀nà mi! Kíákíá ni èmi ìbá kọjú ìjà sí àwọn ọ̀tá wọn,tí ǹ bá sì ṣẹgun wọn. Àwọn tí ó kórìíra OLUWA yóo fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba fún un,ìyà óo sì jẹ wọ́n títí lae. Ṣugbọn èmi ó máa fi ọkà tí ó dára jùlọ bọ yín,n óo sì fi oyin inú àpáta tẹ yín lọ́rùn.” Ẹ dárin, ẹ lu samba, ẹ ta hapu dídùn ati lire. Ẹ fọn fèrè ní ọjọ́ oṣù titun, ati níọjọ́ oṣù tí a yà sọ́tọ̀, ati ní ọjọ́ àsè. Nítorí pé àṣẹ ni, fún àwọn ọmọ Israẹli,ìlànà sì ni, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Jakọbu. Ó pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Josẹfu,nígbà tí ó kọlu ilẹ̀ Ijipti.Mo gbọ́ ohùn kan tí n kò gbọ́ rí: tí ó wí pé, “Mo ti sọ àjàgà náà kalẹ̀ lọ́rùn rẹ;mo ti gba agbọ̀n ẹrù kúrò lọ́wọ́ rẹ. Ninu ìnira, o ké pè mí, mo sì gbà ọ́;mo dá ọ lóhùn ninu ìjì ààrá, níbi tí mo fara pamọ́ sí;mo sì dán ọ wò ninu omi odò Meriba. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo báń kìlọ̀ fun yín,àní kí ẹ fetí sílẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Kò gbọdọ̀ sí ọlọrun àjèjì kan kan láàrin yín;ẹ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún oriṣa-koriṣa kan. Ọlọrun, Ọba Àwọn Ọba. Ọlọrun ti jókòó ní ààyè rẹ̀ ninu ìgbìmọ̀ ọ̀run;ó sì ń ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run: “Yóo ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin óo máa fi aiṣododo ṣe ìdájọ́,tí ẹ óo sì máa ṣe ojuṣaaju fún àwọn eniyan burúkú? Ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn ọmọ aláìníbaba;ẹ sì máa ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tí ojú ń pọ́n ati àwọn talaka. Ẹ gba talaka ati aláìní sílẹ̀,ẹ gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.” Wọn kò ní ìmọ̀ tabi òye,wọ́n ń rìn kiri ninu òkùnkùn,títí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé fi mì tìtì. Mo ní, “oriṣa ni yín,gbogbo yín ni ọmọ Ọ̀gá Ògo. Ṣugbọn sibẹsibẹ, ẹ óo kú bí eniyan,ẹ ó sùn bí èyíkéyìí ninu àwọn ìjòyè.” Dìde, Ọlọrun, ṣe ìdájọ́ ayé,nítorí tìrẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè! Adura Ìṣẹ́gun. Ọlọrun, má dákẹ́;má wòran; Ọlọrun má dúró jẹ́ẹ́! àwọn tí o parun ní Endori,tí wọ́n di ààtàn lórí ilẹ̀. Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí o ti ṣe Orebu ati Seebu;ṣe àwọn ìjòyè wọn bí o ti ṣe Seba ati Salumuna, àwọn tí ó wí pé,“Ẹ jẹ́ kí á mú lára ilẹ̀ Ọlọrunkí á sọ ọ́ di tiwa.” Ọlọrun mi, ṣe wọ́n bí ààjà tíí ṣe ewé,àní, bí afẹ́fẹ́ tíí ṣe fùlùfúlù. Bí iná tíí jó igbó,àní, bí ọwọ́ iná sì ṣe ń jó òkè kanlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì rẹ lé wọn,kí o sì fi ààjà rẹ dẹ́rù bà wọ́n. Da ìtìjú bò wọ́n,kí wọn lè máa wá ọ kiri, OLUWA. Jẹ́ kí ojú tì wọ́n, kí ìdààmú dé bá wọn títí lae,kí wọn sì ṣègbé ninu ìtìjú. Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ nìkan,tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA,ni Ọ̀gá Ògo lórí gbogbo ayé. Wò ó! Àwọn ọ̀tá rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ;àwọn tí ó kórìíra rẹ sì ń yájú sí ọ. Wọ́n pète àrékérekè sí àwọn eniyan rẹ;wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ sí àwọn tí ó sá di ọ́. Wọ́n ní, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa orílẹ̀-èdè wọn run;kí á má ranti orúkọ Israẹli mọ́!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ pète pèrò;wọ́n dá majẹmu láti dojú kọ ọ́. Àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Iṣimaeli,àwọn ará Moabu, ati àwọn ọmọ Hagiri, àwọn ará Gebali, àwọn ọmọ Amoni, ati àwọn ọmọ Amaleki,àwọn ará Filistia ati àwọn tí ń gbé Tire. Àwọn ará Asiria pàápàá ti dara pọ̀ mọ́ wọn;àwọn ni alátìlẹ́yìn àwọn ọmọ Lọti. Ṣe wọ́n bí o ti ṣe àwọn ará Midiani,bí o ti ṣe Sisera ati Jabini ni odò Kiṣoni, Ṣíṣàárò Ilé Ọlọrun. Ibùgbé rẹ lẹ́wà pupọ, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Nítorí pé ọjọ́ kan péré ninu àgbàlá rẹ,ṣe anfaani ju ẹgbẹrun ọjọ́ níbòmíràn lọ.Ó wù mí kí n jẹ́ aṣọ́nà ninu ilé Ọlọrun miju pé kí n máa gbé inú àgọ́ àwọn eniyan burúkú. Nítorí OLUWA Ọlọrun ni oòrùn ati ààbò wa,òun níí ṣeni lóore, tíí dáni lọ́lá,nítorí OLUWA kò ní rowọ́ láti fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ mọ́ní ohun tí ó dára. OLUWA àwọn ọmọ ogun,ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ. ọkàn àgbàlá tẹmpili OLUWA ń fà mí,àárò rẹ̀ ń sọ mí;tọkàn-tara ni mo fi ń kọrin ayọ̀sí Ọlọrun alààyè. Àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ pàápàá a máa kọ́ ilé,àwọn alápàáǹdẹ̀dẹ̀ a sì máa tẹ́ ìtẹ́níbi tí wọ́n ń pa ọmọ sí, lẹ́bàá pẹpẹ rẹ,àní lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun,ọba mi, ati Ọlọrun mi. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń gbé inú ilé rẹ,wọn óo máa kọ orin ìyìn sí ọ títí lae! Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó fi ọ́ ṣe agbára wọn,tí ìrìn àjò sí Sioni jẹ wọ́n lógún. Bí wọ́n ti ń la àfonífojì Baka lọ,wọ́n ń sọ ọ́ di orísun omi;àkọ́rọ̀ òjò sì mú kí adágún omi kún ibẹ̀. Wọn ó máa ní agbára kún agbára,títí wọn ó fi farahàn níwájú Ọlọrun ní Sioni. OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, gbọ́ adura mi;tẹ́tí sílẹ̀, Ọlọrun Jakọbu! Bojú wo àpáta wa, Ọlọrun,fi ojú àánú wo ẹni àmì òróró rẹ. Adura Ire Orílẹ̀-Èdè. OLUWA, o fi ojurere wo ilẹ̀ rẹ;o dá ire Jakọbu pada. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ yóo pàdé;òdodo ati alaafia yóo dì mọ́ ara wọn. Òtítọ́ yóo rú jáde láti inú ilẹ̀;òdodo yóo sì bojú wolẹ̀ láti ojú ọ̀run. Dájúdájú, OLUWA yóo fúnni ní ohun tí ó dára;ilẹ̀ wa yóo sì mú èso jáde lọpọlọpọ. Òdodo yóo máa rìn lọ níwájú rẹ̀,yóo sì sọ ipasẹ̀ rẹ̀ di ọ̀nà. O dárí àìdára àwọn eniyan rẹ jì wọ́n;o sì bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. O mú ìrúnú rẹ kúrò;o dáwọ́ ibinu gbígbóná rẹ dúró. Tún mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun Olùgbàlà wa;dáwọ́ inú tí ń bí ọ sí wa dúró. Ṣé o óo máa bínú sí wa títí lae ni?Ṣé ibinu rẹ yóo máa tẹ̀síwájú láti ìran dé ìran ni? Ṣé o ò ní tún sọ wá jí ni,kí àwọn eniyan rẹ lè máa yọ̀ ninu rẹ? Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn wá, OLUWA;kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ. Jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Ọlọrun, OLUWA yóo wí,nítorí pé ọ̀rọ̀ alaafia ni yóo sọ fún àwọn eniyan rẹ̀,àní, àwọn olùfọkànsìn rẹ̀,ṣugbọn kí wọn má yipada sí ìwà òmùgọ̀. Nítòótọ́, ìgbàlà rẹ̀ wà nítòsí fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;kí ògo rẹ̀ lè wà ní ilẹ̀ wa. Adura Ìrànlọ́wọ́. Tẹ́tí sí mi OLUWA, kí o sì gbọ́ adura mi,nítorí òtòṣì ati aláìní ni mí. Nítorí pé o tóbi, o sì ń ṣe ohun ìyanu;ìwọ nìkan ni Ọlọrun. OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ;kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ. Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi;n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi sí mi;o ti yọ ọkàn mi kúrò ninu isà òkú. Ọlọrun, àwọn agbéraga dìde sí mi;ẹgbẹ́ àwọn ìkà, aláìláàánú kan ń lépa ẹ̀mí mi;wọn kò sì bìkítà fún ọ. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore;o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́. Kọjú sí mi, kí o sì ṣàánú mi;fún èmi iranṣẹ rẹ ní agbára rẹ;kí o sì gba èmi ọmọ iranṣẹbinrin rẹ là. Fi àmì ojurere rẹ hàn mí,kí àwọn tí ó kórìíra mi lè rí i,kí ojú sì tì wọ́n;nítorí pé ìwọ, OLUWA, ni o ràn mí lọ́wọ́,tí o sì tù mí ninu. Dá ẹ̀mí mi sí nítorí olùfọkànsìn ni mí;gba èmi iranṣẹ rẹ tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là;ìwọ ni Ọlọrun mi. Ṣàánú mi, OLUWA,nítorí ìwọ ni mò ń kígbe pè tọ̀sán-tòru. Mú inú iranṣẹ rẹ dùn,nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí. Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA,o máa ń dárí jini;ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́. Fetí sí adura mi, OLUWA,gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ mi. Ní ọjọ́ ìpọ́njú mo ké pè ọ́,nítorí pé o máa ń gbọ́ adura mi. OLUWA, kò sí èyí tí ó dàbí rẹ ninu àwọn oriṣa;kò sì sí iṣẹ́ ẹni tí ó dàbí iṣẹ́ rẹ. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dá ni yóo wá,OLUWA, wọn óo máa forí balẹ̀ níwájú rẹ:wọn óo sì máa yin orúkọ rẹ lógo. Ìyìn Sioni. Ní orí òkè mímọ́ ni ìlú tí OLUWA tẹ̀dó wà. OLUWA fẹ́ràn ẹnubodè Sioni ju gbogbo ìlúyòókù lọ ní ilẹ̀ Jakọbu. Ọpọlọpọ nǹkan tó lógo ni a sọ nípa rẹ,ìwọ ìlú Ọlọrun. Tí mo bá ń ka àwọn ilẹ̀ tí ó mọ rírì mi,n óo dárúkọ Ijipti ati Babiloni,Filistia ati Tire, ati Etiopia.Wọn á máa wí pé, “Ní Jerusalẹmu ni wọ́n ti bí eléyìí.” A óo wí nípa Sioni pé,“Ibẹ̀ ni a ti bí eléyìí ati onítọ̀hún,”nítorí pé Ọ̀gá Ògo yóo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. OLUWA yóo ṣírò rẹ̀ mọ́ wọnnígbà tí ó bá ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé,“Ní Sioni ni a ti bí eléyìí.” Àwọn akọrin ati àwọn afunfèrè ati àwọn tí ń jó yóo máa sọ pé,“Ìwọ, Sioni, ni orísun gbogbo ire wa.” Adura nígbà ìpọ́njú. OLUWA, Ọlọrun, Olùgbàlà mi, mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ ní ọ̀sán;mo ké níwájú rẹ ní òru. Ṣé òkú ni o óo ṣe iṣẹ́ ìyanu hàn?Ṣé àwọn òkú lè dìde kí wọ́n máa yìn ọ́? Ṣé a lè sọ̀rọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ninu ibojì?Àbí ẹnìkan lè sọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ ninu ìparun? Ṣé a lè rí iṣẹ́ ìyanu rẹ ninu òkùnkùn ikú?Àbí ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ wà ní ilẹ̀ àwọn tí a ti gbàgbé? Ṣugbọn OLUWA, èmi ń ké pè ọ́;ní òwúrọ̀ n óo gbadura sí ọ. OLUWA, kí ló dé tí o fi ta mí nù?Kí ló dé tí o fi ojú pamọ́ fún mi? Láti ìgbà èwe mi ni a tí ń jẹ mí níyà,tí mo sì fẹ́rẹ̀ kú,mo ti rí ìjẹníyà rẹ tí ó bani lẹ́rù;agara sì ti dá mi. Ìrúnú rẹ bò mí mọ́lẹ̀;ẹ̀rù rẹ sì bà mí dójú ikú. Wọ́n yí mi ká tọ̀sán-tòru bí ìṣàn omi ńlá;wọ́n ká mi mọ́ patapata. O ti mú kí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi ati àwọn alábàárìn mi kọ̀ mí sílẹ̀;òkùnkùn nìkan ni ó yí mi ká níbi gbogbo. Jẹ́ kí adura mi dé ọ̀dọ̀ rẹ;tẹ́tí sí igbe mi. Nítorí pé ọkàn mi kún fún ìyọnu;mo sì súnmọ́ isà òkú. Mo dàbí àwọn tí ó ń wọ ibojì lọ;mo dà bí ẹni tí kò lágbára mọ. N kò yàtọ̀ sí ẹni tí a pa tì sí apá kan láàrin àwọn òkú,mo dàbí ẹni tí a pa, tí ó sùn ninu ibojì,bí àwọn tí ìwọ kò ranti mọ́,nítorí pé wọ́n ti kúrò lábẹ́ ìtọ́jú rẹ. O ti fi mí sinu isà òkú tí ó jìn pupọ,ninu òkùnkùn, àní ninu ọ̀gbun. Ọwọ́ ibinu rẹ wúwo lára mi,ìgbì ìrúnú rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀. O ti mú kí àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi fi mí sílẹ̀;mo sì ti di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn:mo wà ninu àhámọ́, n kò sì lè jáde; ojú mi ti di bàìbàì nítorí ìbànújẹ́.Lojoojumọ ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA;tí mò ń tẹ́wọ́ adura sí ọ. Majẹmu Ọlọrun pẹlu Dafidi . OLUWA, n óo máa kọrin ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ títí lae;n óo máa fi ẹnu mi kéde òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran. Ìwọ ni o wó Rahabu mọ́lẹ̀ bí òkú ẹran;o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká. Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé pẹlu;ìwọ ni o tẹ ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ dó. Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù,òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀yin orúkọ rẹ. Alágbára ni ọ́;agbára ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;o gbé ọwọ́ agbára rẹ sókè. Òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ;ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ ń lọ ṣiwaju rẹ. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì,àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA, àwọn tí ń yọ̀ nítorí orúkọ rẹ tọ̀sán-tòru,tí sì ń gbé òdodo rẹ lárugẹ. Nítorí ìwọ ni ògo ati agbára wọn;nípa ojurere rẹ sì ni a ti ní ìṣẹ́gun. Dájúdájú, OLUWA, tìrẹ ni ààbò wa;ìwọ, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ọba wa. Ní ìgbàanì, o sọ ninu ìran fún olùfọkànsìn rẹ pé,“Mo ti fi adé dé alágbára kan lórí,mo ti gbé ẹnìkan ga tí a yàn láàrin àwọn eniyan. Nítorí pé, a ti fi ìdí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ múlẹ̀ títí lae;o sì ti fi ìdí òtítọ́ rẹ múlẹ̀ bí ojú ọ̀run. Mo ti rí Dafidi, iranṣẹ mi;mo ti fi òróró mímọ́ mi yàn án; kí ọwọ́ agbára mi lè máa gbé e ró títí lae,kí ọwọ́ mi sì máa fún un ní okun. Ọ̀tá kan kò ní lè borí rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan burúkú kò ní tẹ orí rẹ̀ ba. N óo run ọ̀tá rẹ̀ níwájú rẹ̀;n óo sì bá àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ kanlẹ̀. Òtítọ́ mi ati ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ yóo wà pẹlu rẹ̀;orúkọ mi ni yóo sì máa fi ṣẹgun. N óo mú ìjọba rẹ̀ gbòòrò dé òkun;agbára rẹ̀ yóo sì tàn dé odò Yufurate Yóo ké pè mí pé, ‘Ìwọ ni Baba mi,Ọlọrun mi, ati Àpáta ìgbàlà mi.’ N óo fi ṣe àkọ́bí,àní, ọba tí ó tóbi ju gbogbo ọba ayé lọ. N óo máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn án títí lae;majẹmu èmi pẹlu rẹ̀ yóo sì dúró ṣinṣin. Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae;ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa bẹ níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ. O sọ pé, “Mo ti dá majẹmu kan pẹluẹni tí mo yàn,mo ti búra fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé, “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀,tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi, bí wọ́n bá tàpá sí àṣẹ mi,tí wọn kò sì pa òfin mi mọ́; n óo nà wọ́n lẹ́gba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,n óo sì nà wọ́n ní pàṣán nítorí àìdára wọn. Ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kò ní kúrò lára rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yẹ òtítọ́ mi. N kò ni yẹ majẹmu mi,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ pada. “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ìwà mímọ́ mi búra:n kò ní purọ́ fún Dafidi. Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae,ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa wà níwájú mi, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń yọ. A óo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí òṣùpá títí lae,yóo dúró ṣinṣin níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.” Ṣugbọn nisinsinyii inú rẹ ti ru sí ẹni àmì òróró rẹ;o ti ta á nù,o sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. O ti pa majẹmu tí o bá iranṣẹ rẹ dá tì,o ti ba adé rẹ̀ jẹ́, o ti fi wọ́lẹ̀. ‘N óo fi ìdí àwọn ọmọ rẹ múlẹ̀ títí lae,n óo sì gbé ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ” O ti wó gbogbo odi rẹ̀;o sì ti sọ ilé ìṣọ́ rẹ̀ di ahoro. Gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ ní ń kó o lẹ́rù;ó ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀. O ti ran àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́;o ti mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ yọ̀ ọ́. Àní, o ti ba gbogbo ohun ìjà rẹ̀ jẹ́,o kò sì ràn án lọ́wọ́ lójú ogun. O ti gba ọ̀pá àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀;o sì ti wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀. O ti gé ìgbà èwe rẹ̀ kúrú;o sì ti da ìtìjú bò ó. Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé títí lae ni o óo máa fi ara pamọ́ fún mi?Yóo ti pẹ́ tó tí ibinu rẹ yóo máa jò bí iná? OLUWA, ranti bí ọjọ́ ayé ẹ̀dá ti gùn mọ,ati pé ẹ̀dá lásán ni ọmọ eniyan! Ta ló wà láyé tí kò ní kú?Ta ló lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ́wọ́ agbára isà òkú? OLUWA, níbo ni ìfẹ́ rẹ ìgbàanì tí kì í yẹ̀ wà,tí o búra fún Dafidi pẹlu òtítọ́ rẹ? Jẹ́ kí ojú ọ̀run máa kọrin ìyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ, OLÚWA;kí àwọn eniyan mímọ́ sì máa kọrin ìyìn òtítọ́ rẹ. OLUWA, ranti bí èmi, iranṣẹ rẹ, ti di ẹni yẹ̀yẹ́;ati bí mo ti ń farada ẹ̀gàn àwọn eniyan, OLUWA àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ẹni tí o fi àmì òróró yàn ṣe yẹ̀yẹ́,wọ́n sì ń kẹ́gàn ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀. Ẹni ìyìn ni OLUWA títí lae!Amin! Amin! Nítorí ta ni a lè fi wé ọ ní ọ̀run, OLUWA?Ta ni ó dàbí OLUWA láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run? Ọlọrun, ìwọ ni a bẹ̀rù ninu ìgbìmọ̀ àwọn eniyan mímọ́,o tóbi, o sì lẹ́rù ju gbogbo àwọn tí ó yí ọ ká lọ? OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, ta ló lágbára bíi rẹ?OLUWA, òtítọ́ rẹ yí ọ ká. Ò ń jọba lórí òkun tí ń ru;nígbà tí ìgbì rẹ̀ bá ru sókè, ìwọ ni ò ń mú kí ó rọlẹ̀. Ọpẹ́ fún Ọlọrun nítorí Ìdájọ́ Òdodo Rẹ̀. OLUWA, tọkàntọkàn ni n óo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ;n óo ròyìn gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ. Àwọn tí ó mọ̀ ọ́ yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ;nítorí ìwọ, OLUWA, kìí kọ àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀. Ẹ kọrin ìyìn sí OLUWA, tí ó gúnwà ní Sioni!Ẹ kéde iṣẹ́ rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè! Nítorí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ranti,kò sì gbàgbé igbe ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú. OLUWA, ṣàánú fún mi!Wò ó bí àwọn ọ̀tá mi ṣe ń pọ́n mi lójú.Gbà mí kúrò létí bèbè ikú, kí n lè kọrin ìyìn rẹ,kí n sì lè yọ ayọ̀ ìgbàlà rẹ lẹ́nu ibodè Sioni. Àwọn orílẹ̀-èdè ti jìn sinu kòtò tí wọ́n gbẹ́,wọ́n sì ti kó sinu àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀. OLUWA ti fi ara rẹ̀ hàn, ó ti ṣe ìdájọ́,àwọn eniyan burúkú sì ti kó sinu tàkúté ara wọn. Àwọn eniyan burúkú,àní, gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọrun, ni yóo lọ sinu isà òkú. Nítorí pé OLUWA kò ní fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn aláìní,bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn talaka kò ní já sí òfo títí lae. Dìde, OLUWA, má jẹ́ kí eniyan ó borí,jẹ́ kí á ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè níwájú rẹ. N óo yọ̀, inú mi yóo sì máa dùn nítorí rẹ;n óo kọ orin ìyìn orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ. OLUWA, da ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ bò wọ́n,jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé aláìlágbára eniyan ni àwọn. Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà,wọ́n ṣubú, wọ́n sì parun níwájú rẹ. Nítorí ìwọ ni o fi ìdí ẹ̀tọ́ mi múlẹ̀, tí o sì dá mi láre;ìwọ ni o jókòó lórí ìtẹ́, o sì ṣe ìdájọ́ òdodo. O bá àwọn orílẹ̀-èdè wí,o pa àwọn eniyan burúkú run,o sì pa orúkọ wọn rẹ́ títí lae. O pa àwọn ọ̀tá run patapata, o sọ ìlú wọn di ahoro,o sì sọ wọ́n di ẹni ìgbàgbé. Ṣugbọn OLUWA gúnwà títí lae,ó ti fi ìdí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀ múlẹ̀. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé,yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè. OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú. Ibi tí Agbára Ẹ̀dá Mọ. OLUWA, ìwọ ni o ti jẹ́ ibi ààbò wa láti ìrandíran. Aadọrin ọdún ni ọjọ́ ayé wa;pẹlu ipá a lè tó ọgọrin;sibẹ gbogbo rẹ̀ jẹ́ kìkì làálàá ati ìyọnu;kíá, ayé wa á ti dópin, ẹ̀mí wa á sì fò lọ. Ta ló mọ agbára ibinu rẹ?Ta ló sì mọ̀ pé bí ẹ̀rù rẹ ti tó bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ rí? Nítorí náà kọ́ wa láti máa ka iye ọjọ́ orí wa,kí á lè kọ́gbọ́n. Yipada sí wa, OLUWA; yóo ti pẹ́ tó tí o óo máa bínú sí wa?Ṣàánú àwa iranṣẹ rẹ. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀,kí á lè máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùnní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Mú inú wa dùn fún iye ọjọ́ tí oti fi pọ́n wa lójú,ati fún iye ọdún tí ojú wa ti fi rí ibi. Jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ,kí agbára rẹ tí ó lógo sì hàn sí àwọn ọmọ wọn. Jẹ́ kí ojurere OLUWA Ọlọrun wa wà lára wa,fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀,jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wa fi ìdí múlẹ̀. Kí o tó dá àwọn òkè,ati kí o tó dá ilẹ̀ ati ayé,láti ayérayé, ìwọ ni Ọlọrun. O sọ eniyan di erùpẹ̀ pada,o sì wí pé, “Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ eniyan.” Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹrun ọdún dàbí àná,tabi bí ìṣọ́ kan ní òru. Ìwọ a máa gbá ọmọ eniyan dànù; wọ́n dàbí àlá,bíi koríko tí ó tutù ní òwúrọ̀; ní òwúrọ̀ á máa gbilẹ̀, á sì máa jí pérépéré;ní ìrọ̀lẹ́ á sá, á sì rọ. Ibinu rẹ pa wá run;ìrúnú rẹ sì bò wá mọ́lẹ̀. O ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa kalẹ̀ ní iwájú rẹ;àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa sì hàn kedere ninu ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ. Nítorí ọjọ́ ayé wa ń kọjá lọ ninu ibinu rẹ;ayé wa sì ń dópin bí ẹni mí kanlẹ̀. Ọlọrun Aláàbò wa. Ẹni tí ń gbé abẹ́ ààbò Ọ̀gá Ògo,tí ó wà lábẹ́ òjìji Olodumare, ibi kankan kò ní dé bá ọ,bẹ́ẹ̀ ni àjálù kankan kò ní súnmọ́ ilé rẹ. Nítorí yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀, nítorí rẹ,pé kí wọ́n máa pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ. Wọ́n óo fi ọwọ́ wọn gbé ọ sókè,kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta. O óo rìn kọjá lórí kinniun ati paramọ́lẹ̀;ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ati ejò ńlá ni o óo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. OLUWA ní, “Nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí mi,n óo gbà á là;n óo dáàbò bò ó, nítorí pé ó mọ orúkọ mi. Yóo pè mí, n óo sì dá a lóhùn;n óo wà pẹlu rẹ̀ ninu ìṣòro,n óo yọ ọ́ ninu rẹ̀, n óo dá a lọ́lá. N óo fi ẹ̀mí gígùn tẹ́ ẹ lọ́rùn,n óo sì gbà á là.” yóo wí fún OLUWA pé,“Ìwọ ni ààbò ati odi mi,Ọlọrun mi, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé.” Nítorí yóo yọ ọ́ ninu okùn àwọn pẹyẹpẹyẹati ninu àjàkálẹ̀ àrùn apanirun. Yóo da ìyẹ́ rẹ̀ bò ọ́,lábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ ni o óo ti rí ààbò;òtítọ́ rẹ̀ ni yóo jẹ́ asà ati apata rẹ. O ò ní bẹ̀rù ìdágìrì òru,tabi ọfà tí ń fò kiri ní ọ̀sán, tabi àjàkálẹ̀ àrùn tí ń jà kiri ninu òkùnkùn,tabi ìparun tí ń ṣeni lófò ní ọ̀sán gangan. Ẹgbẹrun lè ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,tabi ẹgbaarun ni apá ọ̀tún rẹ;ṣugbọn kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ. Ojú nìkan ni óo kàn máa fi rí wọn,tí o óo sì máa fi wo èrè àwọn eniyan burúkú. Nítorí tí ìwọ ti fi OLUWA ṣe ààbò rẹ,o sì ti fi Ọ̀gá Ògo ṣe ibùgbé rẹ, Orin Ìyìn. Ó dára kí eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA;kí ó sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá Ògo; Ṣugbọn o ti gbé mi ga, o ti fún mi lágbára bíi ti ẹfọ̀n;o ti da òróró dáradára sí mi lórí. Mo ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi,mo sì ti fi etí mi gbọ́ ìparun àwọn ẹni ibi tí ó gbé ìjà kò mí. Àwọn olódodo yóo gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹ,wọn óo dàgbà bí igi kedari ti Lẹbanoni. Wọ́n dàbí igi tí a gbìn sí ilé OLUWA,tí ó sì ń dàgbà ninu àgbàlá Ọlọrun wa. Wọn á máa so èso títí di ọjọ́ ogbó wọn,wọn á máa lómi lára, ewé wọn á sì máa tutù nígbà gbogbo; láti fihàn pé olóòótọ́ ni OLUWA;òun ni àpáta mi, kò sì sí aiṣododo lọ́wọ́ rẹ̀. ó dára kí eniyan máa kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ní òwúrọ̀,kí ó máa kéde òtítọ́ rẹ ní alẹ́, pẹlu orin, lórí ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá,ati hapu. Nítorí ìwọ, OLUWA, ti mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ;OLUWA, mò ń fi ayọ̀ kọrin nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tóbi pupọ, OLÚWA!Èrò rẹ sì jinlẹ̀ pupọ! Òpè eniyan kò lè mọ̀,kò sì le yé òmùgọ̀: pé bí eniyan burúkú bá tilẹ̀ rú bíi koríko,tí gbogbo àwọn aṣebi sì ń gbilẹ̀,ó dájú pé ìparun ayérayé ni òpin wọn. Ṣugbọn ẹni àgbéga títí lae ni ọ́, OLUWA. Wò ó, OLUWA, àwọn ọ̀tá rẹ yóo parun;gbogbo àwọn aṣebi yóo sì fọ́n ká. Ọlọrun Ọba. OLUWA jọba; ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí ẹ̀wù;OLUWA gbé ọlá ńlá wọ̀,ó sì di agbára ni àmùrè.Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;kò sì ní yẹ̀ laelae. A ti fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ láti ìgbà laelae;láti ayérayé ni o ti wà. Ibú omi gbé ohùn wọn sókè, OLUWA,ibú omi gbé ohùn wọn sókè,ó sì ń sán bí ààrá. OLUWA lágbára lókè!Ó lágbára ju ariwo omi òkun lọ,ó lágbára ju ìgbì omi òkun lọ. Àwọn òfin rẹ kìí yipada,ìwà mímọ́ ni ó yẹ ilé rẹ títí lae, OLUWA. Ọlọrun Onídàájọ́ Gbogbo Ayé. OLUWA, ìwọ Ọlọrun ẹ̀san,ìwọ Ọlọrun ẹ̀san, fi agbára rẹ hàn! Ṣé ẹni tí ń jẹ àwọn orílẹ̀-èdè níyà,ni kò ní jẹ yín níyà?Àbí ẹni tí ń fún eniyan ní ìmọ̀, ni kò ní ní ìmọ̀? OLUWA mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan,ó mọ̀ pé afẹ́fẹ́ lásán ni. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o bá báwí, OLUWA,tí o sì kọ́ ní òfin rẹ, kí ó lè sinmi lọ́wọ́ ọjọ́ ìṣòro,títí tí a ó fi gbẹ́ kòtò fún eniyan burúkú. Nítorí OLUWA kò ní kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀;kò ní ṣá àwọn eniyan ìní rẹ̀ tì; nítorí pé ìdájọ́ òtítọ́ yóo pada jẹ́ ìpín àwọn olódodo,àwọn olóòótọ́ yóo sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn eniyan burúkú?Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn aṣebi? Bí kì í bá ṣe pé OLUWA ràn mí lọ́wọ́,ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní isà òkú. Nígbà tí mo rò pé, “Ẹsẹ̀ mi ti yọ̀,”OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni ó gbé mi ró. Nígbà tí àìbàlẹ̀ ọkàn mi pọ̀ pupọ,ìwọ ni o tù mí ninu, tí o dá mi lọ́kàn le. Dìde, ìwọ onídàájọ́ ayé;san ẹ̀san èrè iṣẹ́ àwọn agbéraga fún wọn! Ǹjẹ́ o lè ní àjọṣe pẹlu àwọn ìkà aláṣẹ,àwọn tí ń fi òfin gbé ìwà ìkà ró? Wọ́n para pọ̀ láti gba ẹ̀mí olódodo;wọ́n sì dá ẹjọ́ ikú fún aláìṣẹ̀. Ṣugbọn OLUWA ti di ibi ìsádi mi,Ọlọrun mi sì ti di àpáta ààbò mi. Yóo san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn,yóo pa wọ́n run nítorí ìwà ìkà wọn.OLUWA Ọlọrun wa yóo pa wọ́n run. OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?Àní, yóo ti pẹ́ tó tí àwọn eniyan burúkú yóo máa ṣe jàgínní? Wọ́n ń fi ìgbéraga sọ̀rọ̀ jàbùjàbù,gbogbo àwọn aṣebi ní ń fọ́nnu. Wọ́n ń rún àwọn eniyan rẹ mọ́lẹ̀, OLUWA,wọ́n ń pọ́n àwọn eniyan rẹ lójú. Wọ́n ń pa àwọn opó ati àwọn àlejò,wọ́n sì ń pa àwọn aláìníbaba; wọ́n ń sọ pé, “OLUWA kò rí wa;Ọlọrun Jakọbu kò ṣàkíyèsí wa.” Ẹ jẹ́ kí ó ye yín,ẹ̀yin tí ẹ ya òpè jùlọ láàrin àwọn eniyan!Ẹ̀yin òmùgọ̀, nígbà wo ni ẹ óo gbọ́n? Ṣé ẹni tí ó dá etí, ni kò ní gbọ́ràn?Àbí ẹni tí ó dá ojú, ni kò ní ríran? Orin Ìyìn. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọrin sí OLUWA;ẹ jẹ́ kí á hó ìhó ayọ̀ sí Olùdáàbòbò ati ìgbàlà wa! Fún ogoji ọdún gbáko ni ọ̀rọ̀ wọn fi sú mi,tí mo sọ pé, “Ọkàn àwọn eniyan wọnyi ti yapa,wọn kò sì bìkítà fún ìlànà mi.” Nítorí náà ni mo fi fi ibinu búra pé,wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi. Ẹ jẹ́ kí á wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọpẹ́;ẹ jẹ́ kí á fi orin ìyìn hó ìhó ayọ̀ sí i. Nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi ni OLUWA,ọba tí ó tóbi ni, ó ju gbogbo oriṣa lọ. Ìkáwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà;gíga àwọn òkè ńlá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pẹlu. Tirẹ̀ ni òkun, nítorí pé òun ni ó dá a;ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á jọ́sìn, kí á tẹríba,ẹ jẹ́ kí á kúnlẹ̀ níwájú OLUWA, Ẹlẹ́dàá wa! Nítorí òun ni Ọlọrun wa,àwa ni eniyan rẹ̀, tí ó ń kó jẹ̀ káàkiri,àwa ni agbo aguntan rẹ̀.Bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀ lónìí, ẹ má ṣe orí kunkun bí ẹ ti ṣe ní Meriba,ati bí ẹ ti ṣe ní ijọ́un ní Masa, ninu aṣálẹ̀ nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò,tí wọ́n dẹ mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ríohun tí mo ti ṣe rí. Ọlọrun Ọba Àwọn Ọba. Ẹ kọ orin titun sí OLUWA;gbogbo ayé, ẹ kọ orin sí OLUWA. Ẹ wí láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé, “OLUWA jọba!A ti fi ìdí ayé múlẹ̀, kò sì ní yẹ̀ lae;OLUWA yóo fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.” Jẹ́ kí inú ọ̀run ó dùn, sì jẹ́ kí ayé ó yọ̀;kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Jẹ́ kí pápá oko ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ yọ̀.Nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóo fi ayọ̀ kọrin, níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀;ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;yóo sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan. Ẹ kọ orin sí OLUWA, ẹ yin orúkọ rẹ̀;ẹ sọ nípa ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́. Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;ẹ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan. Nítorí OLUWA tóbi, ó yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ;ó sì yẹ kí á bẹ̀rù rẹ̀ ju gbogbo oriṣa lọ. Nítorí oriṣa lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń sìn,ṣugbọn OLUWA ni ó dá ọ̀run. Iyì ati ọlá ńlá ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀;agbára ati ẹwà kún inú ilé mímọ́ rẹ̀. Ẹ yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin aráyé;ẹ kókìkí ògo ati agbára rẹ̀. Ẹ fún OLUWA ní iyì tí ó tọ́ sí orúkọ rẹ̀,ẹ mú ọrẹ lọ́wọ́ wá sinu àgbàlá rẹ̀. Ẹ sin OLUWA ninu ẹwà ìwà mímọ́;gbogbo ayé, ẹ wárìrì níwájú rẹ̀. Ọlọrun Ọba Atóbijù. OLUWA jọba, kí ayé ó yọ̀;jẹ́ kí inú ogunlọ́gọ̀ erékùṣù ó dùn. Ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn OLUWA, ẹ kórìíra ibi;OLUWA á máa dá ẹ̀mí àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sí,a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú. Ìmọ́lẹ̀ á máa tàn fún àwọn olódodo,ayọ̀ sì wà fún àwọn olótìítọ́ inú. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo,kí ẹ sì máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀. Ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri ni ó yí i ká;òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀. Iná ń jó lọ níwájú rẹ̀,ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́tùn-ún lósì. Mànàmáná rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé,ilẹ̀ ayé rí i, ó sì wárìrì. Àwọn òkè ńlá yọ́ bí ìda níwájú OLUWA,àní, níwájú OLUWA gbogbo ayé. Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀;gbogbo orílẹ̀-èdè sì ń wo ògo rẹ̀. Ojú ti gbogbo àwọn tí ń bọ oriṣa,àwọn tí ń fi ère lásánlàsàn yangàn;gbogbo oriṣa ní ń foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀. Àwọn ará Sioni gbọ́, inú wọn dùn.Àwọn ará ìlú Juda sì ń yọ̀,nítorí ìdájọ́ rẹ, OLUWA. Nítorí ìwọ OLUWA ni Ọ̀gá Ògo,o ju gbogbo ayé lọ,a gbé ọ ga ju gbogbo oriṣa lọ. Ọlọrun, Ọba gbogbo Ayé. Ẹ kọ orin titun sí OLUWA,nítorí tí ó ti ṣe ohun ìyanu;agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati apá mímọ́ rẹ̀ ni ó fi ṣẹgun. OLUWA ti sọ ìṣẹ́gun rẹ̀ di mímọ̀,ó ti fi ìdáláre rẹ̀ hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè. Ó ranti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ̀sí àwọn ọmọ Israẹli;gbogbo ayé ti rí ìṣẹ́gun Ọlọrun wa. Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA;ẹ bú sí orin ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn. Ẹ fi hapu kọ orin ìyìn sí OLUWA,àní, hapu ati ohùn orin dídùn. Ẹ fun fèrè ati ìwokí ẹ sì hó ìhó ayọ̀ níwájú OLUWA Ọba. Kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,kí ayé hó, ati àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Omi òkun, ẹ pàtẹ́wọ́;kí ẹ̀yin òkè sì fi ayọ̀ kọrin pọ̀ níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan. Ọlọrun Ọba Atóbijù. OLUWA jọba, kí àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì;ó gúnwà lórí àwọn kerubu; kí ilẹ̀ mì tìtì. OLUWA tóbi ní Sioni,ó sì jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè. Jẹ́ kí wọ́n yin orúkọ rẹ tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù,mímọ́ ni OLUWA! Ọba alágbára, ìwọ tí o fẹ́ràn òdodo,o ti fi ìdí ẹ̀tọ́ múlẹ̀;o ti dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ Jakọbu. Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,ẹ jọ́sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀;mímọ́ ni OLUWA! Mose ati Aaroni wà lára àwọn alufaa rẹ̀;Samuẹli pàápàá wà lára àwọn tí ń pe orúkọ rẹ̀;wọ́n ké pe OLUWA ó sì dá wọn lóhùn. Ó bá wọn sọ̀rọ̀ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu;wọ́n pa òfin rẹ̀ mọ́;wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí ó fún wọn. OLUWA Ọlọrun wa, o dá wọn lóhùn;Ọlọrun tíí dáríjì ni ni o jẹ́ fún wọn;ṣugbọn ó gbẹ̀san ìwàkiwà wọn. Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,kí ẹ sì jọ́sìn níbi òkè mímọ́ rẹ̀;nítorí pé mímọ́ ni OLUWA Ọlọrun wa. Ọ̀rọ̀ Iṣaaju ati Ìkíni. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó níláti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ nìyí, tí Ọlọrun fún Jesu Kristi, pé kí ó fihan àwọn iranṣẹ rẹ̀. Jesu wá rán angẹli rẹ̀ sí Johanu, iranṣẹ rẹ̀, pé kí ó fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà hàn án. Nígbà tí ó di Ọjọ́ Oluwa, ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi bí ìgbà tí fèrè bá ń dún, ó ní, “Kọ ohun tí o bá rí sinu ìwé, kí o fi ranṣẹ sí àwọn ìjọ ní ìlú mejeeje wọnyi: Efesu ati Simana, Pẹgamu ati Tiatira, Sadi ati Filadẹfia ati Laodikia.” Mo bá yipada láti wo ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Bí mo ti yipada, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà meje. Ní ààrin àwọn ọ̀pá fìtílà yìí ni ẹnìkan wà tí ó dàbí eniyan. Ó wọ ẹ̀wù tí ó balẹ̀ dé ilẹ̀. Ó fi ọ̀já wúrà gba àyà. Irun orí rẹ̀ funfun gbòò bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ojú rẹ̀ ń kọ yànràn bí iná. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí idẹ tí ń dán, tí alágbẹ̀dẹ ń dà ninu iná. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi òkun. Ó mú ìràwọ̀ meje lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. Idà olójú meji tí ó mú yọ jáde lẹ́nu rẹ̀. Ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ bí oòrùn ọ̀sán gangan. Nígbà tí mo rí i, mo ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó bá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi. Ó ní, “Má bẹ̀rù. Èmi ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn. Èmi ni ẹni tí ó wà láàyè. Mo kú, ṣugbọn mo ti jí, mo sì wà láàyè lae ati laelae. Àwọn kọ́kọ́rọ́ ikú ati ti ipò òkú wà lọ́wọ́ mi. Nítorí náà kọ àwọn ohun tí o rí sílẹ̀, ati àwọn ohun tí ó wà nisinsinyii ati àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. Johanu sọ gbogbo nǹkan tí ó rí nípa ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati ẹ̀rí Jesu Kristi. Àṣírí ìràwọ̀ meje tí o rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ati ti ọ̀pá fìtílà wúrà meje nìyí: ìràwọ̀ meje ni àwọn angẹli ìjọ meje. Ọ̀pá fìtílà meje ni àwọn ìjọ meje. Ẹni tí ó bá ń ka ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ati àwọn tí ó bá ń gbọ́, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ohun tí a kọ, ṣe oríire. Nítorí àkókò tí yóo ṣẹlẹ̀ súnmọ́ tòsí. Èmi Johanu ni mo ranṣẹ sí ìjọ meje tí ó wà ní agbègbè Esia.Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia wà pẹlu yín láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti wà, tí ó ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, ati láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí meje tí wọ́n wà níwájú ìtẹ́ rẹ̀; ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí òtítọ́, ẹnikinni tí ó jinde láti inú òkú ati aláṣẹ lórí àwọn ọba ilé ayé.Ẹni tí ó fẹ́ràn wa, tí ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó sọ wá di ìjọba, ati alufaa Ọlọrun Baba rẹ̀. Tirẹ̀ ni ògo ati agbára lae ati laelae. Amin. Wò ó! Ó ń bọ̀ ninu awọsanma, gbogbo eniyan ni yóo sì rí i. Àwọn tí wọ́n gún un lọ́kọ̀ náà yóo rí i. Gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóo dárò nígbà tí wọ́n bá rí i. Amin! Àṣẹ! “Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.” Oluwa Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó ti wà, tí ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, Olodumare. Èmi ni Johanu, arakunrin yín ati alábàápín pẹlu yín ninu ìpọ́njú tí ẹni tí ó bá tẹ̀lé Jesu níláti rí, ati ìfaradà tí ó níláti ní. Wọ́n jù mí sí ilẹ̀ kan tí ń jẹ́ Patimosi nítorí mo waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun, mo sì jẹ́rìí pé Jesu ni mo gbàgbọ́. Erékùṣù ni ilẹ̀ Patimosi, ó wà láàrin omi. Angẹli ati Ìwé-kíká Kékeré. Mo tún rí angẹli alágbára mìíràn, tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Ó fi ìkùukùu bora, òṣùmàrè sì yí orí rẹ̀ ká; ojú rẹ̀ dàbí oòrùn; ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí òpó iná. Mo bá gba ìwé náà ní ọwọ́ angẹli yìí, mo bá jẹ ẹ́. Ó dùn bí oyin ní ẹnu mi. Ṣugbọn nígbà tí mo gbé e mì, ó korò ní ikùn mi. Wọ́n bá sọ fún mi pé, “O níláti tún kéde fún ọ̀pọ̀ àwọn eniyan ati oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ati àwọn orílẹ̀-èdè, ati ọpọlọpọ ìjọba.” Ó mú ìwé kékeré kan lọ́wọ́ tí ó wà ní ṣíṣí. Ó gbé ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ lé orí òkun, ó sì gbé ti òsì lé orí ilẹ̀ ayé. Ó wá bú ramúramù bíi kinniun. Nígbà tí ó bú báyìí tán, ààrá meje sán. Nígbà tí ààrá meje yìí ń sán, mo fẹ́ máa kọ ohun tí wọn ń sọ sílẹ̀, ṣugbọn mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run, tí ó sọ pé, “Àṣírí ni ohun tí àwọn ààrá meje yìí ń sọ, má kọ wọ́n sílẹ̀.” Angẹli náà tí mo rí, tí ó gbé ẹsẹ̀ lé orí òkun, ati orí ilẹ̀, wá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sí òkè ọ̀run, ó fi ẹni tí ó wà láàyè lae ati títí laelae búra, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó dá ayé ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó dá òkun ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Ó ní kò sí ìjáfara mọ́. Ní ọjọ́ tí angẹli keje bá fọhùn, nígbà tí ó bá fẹ́ fun kàkàkí tirẹ̀, àṣírí ète Ọlọrun yóo ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. Mo tún gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run tí ó sọ fún mi pé, “Lọ gba ìwé tí ó wà ni ṣíṣí tí ó wà lọ́wọ́ angẹli tí ó dúró lórí òkun ati lórí ilẹ̀.” Mo bá lọ sọ́dọ̀ angẹli náà, mo ní kí ó fún mi ní ìwé kékeré náà. Ó ní, “Gbà, kí o jẹ ẹ́. Yóo dùn ní ẹnu rẹ bí oyin, ṣugbọn yóo korò ní ikùn rẹ.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Meji. Wọ́n fún mi ní ọ̀pá kan, bí èyí tí wọ́n fi ń wọn aṣọ. Wọ́n sọ fún mi pé, “Dìde! Lọ wọn Tẹmpili Ọlọrun ati pẹpẹ ìrúbọ, kí o ka iye àwọn tí wọ́n n jọ́sìn níbẹ̀. Àwọn ọmọ aráyé yóo máa yọ̀ wọ́n, inú wọn yóo sì máa dùn. Wọn yóo máa fún ara wọn lẹ́bùn. Nítorí pé ìyọlẹ́nu ni àwọn akéde meji wọnyi jẹ́ fún àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta ati ààbọ̀ yìí, èémí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wọ inú wọn, ni wọ́n bá jí, wọn bá dìde dúró. Ẹ̀rù ba àwọn tí ó rí wọn gan-an. Wọ́n wá gbọ́ ohùn líle láti ọ̀run wá tí ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá síhìn-ín.” Ni wọ́n bá gòkè lọ sọ́run ninu ìkùukùu, lójú àwọn ọ̀tá wọn. Ilẹ̀ mì tìtì, ìdámẹ́wàá ìlú bá wó. Ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan ni ó kú nígbà tí ilẹ̀ náà mì. Ẹ̀rù ba àwọn tí ó kù, wọ́n sì fi ògo fún Ọlọrun ọ̀run. Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú keji kọjá. Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kẹta fẹ́rẹ̀ dé. Angẹli keje fun kàkàkí rẹ̀, àwọn ohùn líle kan ní ọ̀run bá sọ pé, “Ìjọba ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀. Yóo jọba lae ati laelae.” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ wọn níwájú Ọlọrun bá dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun. Wọ́n ní,“A fi ìyìn fún ọ, Oluwa, Ọlọrun Olodumare,ẹni tí ó wà, tí ó ti wà,nítorí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ń jọba. Inú àwọn orílẹ̀-èdè ru,ṣugbọn àkókò ibinu rẹ dé,ó tó àkókò láti ṣe ìdájọ́ àwọn òkú,ati láti fi èrè fún àwọn iranṣẹ rẹ, àwọn wolii, àwọn eniyan rẹ,ati àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ, ìbáà ṣe àwọn mẹ̀kúnnù tabi àwọn eniyan ńláńlá.Àkókò dé láti pa àwọn tí ó ń ba ayé jẹ́ run.” Tẹmpili Ọlọrun ti ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, tí a fi lè rí àpótí majẹmu ninu rẹ̀. Mànàmáná wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ, ààrá ń sán, ilẹ̀ ń mì tìtì; yìnyín sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ sílẹ̀. Má wulẹ̀ wọn àgbàlá Tẹmpili tí ó wà lóde, nítorí a ti fi fún àwọn alaigbagbọ. Wọn yóo gba ìlú mímọ́ fún oṣù mejilelogoji. N óo fún àwọn ẹlẹ́rìí mi meji láṣẹ láti kéde iṣẹ́ mi fún ọtalelẹgbẹfa (1260) ọjọ́. Aṣọ ọ̀fọ̀ ni wọn yóo wọ̀ ní gbogbo àkókò náà.” Àwọn wọnyi ni igi olifi meji ati ọ̀pá fìtílà meji tí ó dúró níwájú Oluwa ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ pa wọ́n lára, iná ni yóo yọ lẹ́nu wọn, yóo sì jó àwọn ọ̀tá wọn run. Irú ikú bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ṣe wọ́n ní ibi yóo kú. Wọ́n ní àṣẹ láti ti ojú ọ̀run pa, tí òjò kò fi ní rọ̀ ní gbogbo àkókò tí wọn bá ń kéde. Wọ́n tún ní àṣẹ láti sọ gbogbo omi di ẹ̀jẹ̀. Wọ́n sì lè mú kí àjàkálẹ̀ àrùn oríṣìíríṣìí bá ayé, bí wọ́n bá fẹ́. Nígbà tí wọ́n bá parí ẹ̀rí tí wọn níí jẹ́, ẹranko tí ó jáde láti inú kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀, yóo wá bá wọn jagun. Yóo ṣẹgun wọn, yóo sì pa wọ́n. Òkú wọn yóo wà ní títì ìlú ńlá tí a ti kan Oluwa wọn mọ́ agbelebu. Àfiwé orúkọ rẹ̀ ni Sodomu ati Ijipti. Àwọn eniyan láti inú gbogbo ẹ̀yà, ati gbogbo orílẹ̀-èdè yóo máa wo òkú wọn fún ọjọ́ mẹta ati ààbọ̀. Wọn kò ní jẹ́ kí wọ́n sin wọ́n. Obinrin kan ati Ẹranko Ewèlè. Mo wá rí àmì ńlá kan ní ọ̀run. Obinrin kan tí ó fi oòrùn ṣe aṣọ, tí òṣùpá wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó dé adé tí ó ní ìràwọ̀ mejila. Mo wá gbọ́ ohùn líle kan ní ọ̀run tí ó sọ pé, “Àkókò ìgbàlà nìyí ati ti agbára, ati ìjọba ti Ọlọrun wa, ati àkókò àṣẹ Kristi rẹ̀. Nítorí a ti lé Olùfisùn àwọn onigbagbọ ara wa jáde, tí ó ń fi ẹjọ́ wọn sùn níwájú Ọlọrun wa tọ̀sán-tòru. Wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan ati ẹ̀rí ọ̀rọ̀ tí wọ́n jẹ́ ṣẹgun rẹ̀. Nítorí wọn kò ka ẹ̀mí wọn sí pé ó ṣe iyebíye jù kí wọ́n kú lọ. Nítorí náà, ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé inú wọn. Ó ṣe fun yín, ayé, ati fún òkun! Nítorí Èṣù ti dé sáàrin yín. Inú rẹ̀ ń ru, nítorí ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ni ó kù fún òun.” Nígbà tí Ẹranko Ewèlè náà rí i pé a lé òun jáde sinu ayé, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé obinrin tí ó bí ọmọkunrin nnì kiri. Ni a bá fún obinrin náà ní ìyẹ́ idì ńláńlá meji, kí ó lè fò lọ sí aṣálẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀ fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ó fi bọ́ lọ́wọ́ ejò náà. Ni ejò yìí bá tú omi jáde lẹ́nu bí odò, kí omi lè gbé obinrin náà lọ. Ṣugbọn ilẹ̀ ran obinrin náà lọ́wọ́. Ilẹ̀ lanu, ó fa omi tí Ẹranko Ewèlè náà tu jáde lẹ́nu mu. Inú wá bí Ẹranko Ewèlè yìí sí obinrin náà. Ó wá lọ gbógun ti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, tí wọn ń pa àṣẹ Ọlọrun mọ́, tí wọn ń jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu. Ó dúró lórí iyanrìn etí òkun. Obinrin náà lóyún. Ó wá ń rọbí. Ó ń jẹ̀rora bí ó ti fẹ́ bímọ. Mo wá tún rí àmì mìíràn ní ọ̀run: Ẹranko Ewèlè ńlá kan tí ó pupa bí iná, tí ó ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá, ó dé adé meje. Ó fi ìrù gbá ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, wọ́n bá jábọ́ sórí ilẹ̀ ayé. Ẹranko Ewèlè yìí dúró níwájú obinrin tí ó fẹ́ bímọ yìí, ó fẹ́ gbé ọmọ náà jẹ bí ó bá ti bí i tán. Obinrin yìí bí ọmọkunrin, tí yóo jọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè pẹlu ọ̀pá irin. A bá já ọmọ náà gbà lọ sọ́dọ̀ Ọlọrun, níwájú ìtẹ́ rẹ̀. Obinrin yìí bá sálọ sí aṣálẹ̀, níbìkan tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀. Níbẹ̀ ni ó wà lábẹ́ ìtọ́jú fún ẹgbẹfa ọjọ́ ó lé ọgọta (1260). Ogun wá bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run. Mikaeli ati àwọn angẹli rẹ̀ ń bá Ẹranko Ewèlè náà jà. Ẹranko Ewèlè yìí ati àwọn angẹli rẹ̀ náà jà títí, ṣugbọn kò lágbára tó láti ṣẹgun. Wọ́n bá lé òun ati àwọn angẹli rẹ̀ kúrò ní ọ̀run. Wọ́n lé Ẹranko Ewèlè náà jáde–ejò àtijọ́ nì tí à ń pè ní Èṣù, tabi Satani tí ó ń tan àwọn tí ó ń gbé inú ayé jẹ. Wọ́n lé e jáde lọ sinu ayé, ati òun ati àwọn angẹli rẹ̀. Àwọn Ẹranko Meji. Mo wá rí ẹranko kan tí ń ti inú òkun jáde bọ̀. Ó ní ìwo mẹ́wàá ati orí meje. Adé mẹ́wàá wà lórí ìwo rẹ̀. Ó kọ orúkọ àfojúdi sára orí rẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Bí ẹnikẹ́ni bá níláti lọ sí ìgbèkùn, yóo lọ sí ìgbèkùn. Bí ẹnikẹ́ni bá fi idà pa eniyan, idà ni a óo fi pa òun náà. Níhìn-ín ni ìfaradà ati ìdúró ṣinṣin àwọn eniyan Ọlọrun yóo ti hàn. Mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó jáde láti inú ilẹ̀. Ó ní ìwo meji bíi ti Ọ̀dọ́ Aguntan. Ó ń sọ̀rọ̀ bíi ti Ẹranko Ewèlè. Ó ń lo àṣẹ bíi ti ẹranko àkọ́kọ́, lójú ẹranko àkọ́kọ́ fúnrarẹ̀. Ó mú kí ayé ati àwọn tí ó ń gbé inú rẹ̀ júbà ẹranko àkọ́kọ́, tí ọgbẹ́ rẹ̀ ti san. Ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì ńláńlá. Ó mú kí iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sí ayé lójú àwọn eniyan. Ó fi iṣẹ́ abàmì tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà tan àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n yá ère ẹranko tí a ti fi idà ṣá lọ́gbẹ́ tí ó tún yè. A fún un ní agbára láti fi èémí sinu ère ẹranko náà, kí ère ẹranko náà lè fọhùn, kí ó lè pa àwọn tí kò bá júbà ère ẹranko náà. Lẹ́yìn náà, gbogbo eniyan, ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan ńláńlá ati ọlọ́rọ̀ ati talaka, ati ẹrú ati òmìnira ni ẹranko yìí mú kí wọ́n ṣe àmì sí ọwọ́ ọ̀tún tabi iwájú wọn. Kò sí ẹni tí ó lè ra ohunkohun tabi kí ó ta ohunkohun àfi ẹni tí ó bá ní àmì orúkọ ẹranko náà tabi ti iye orúkọ rẹ̀ lára. Ohun tí ó gba ọgbọ́n nìyí. Ẹni tí ó bá ní òye ni ó lè mọ ìtumọ̀ àmì orúkọ ẹranko náà, nítorí pé bí orúkọ eniyan kan gan-an ni àmì yìí rí. Ìtumọ̀ iye àmì náà ni ọtalelẹgbẹta, ó lé mẹfa (666). Ẹranko náà tí mo rí dàbí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí ti ìkookò. Ẹnu rẹ̀ dàbí ti kinniun. Ẹranko Ewèlè náà fún un ní agbára rẹ̀, ati ìtẹ́ rẹ̀ ati àṣẹ ńlá rẹ̀. Ó dàbí ẹni pé wọ́n ti ṣá ọ̀kan ninu àwọn orí ẹranko náà lọ́gbẹ́. Ọgbẹ́ ọ̀hún tó ohun tí ó yẹ kí ó pa á ṣugbọn ó ti jinná. Gbogbo eniyan ni wọ́n ń tẹ̀lé ẹranko yìí tí wọ́n fi ń ṣe ìran wò. Wọ́n ń júbà Ẹranko Ewèlè náà nítorí pé ó fi àṣẹ fún ẹranko yìí. Wọ́n sì ń júbà ẹranko náà, wọ́n ń sọ pé, “Ta ni ó dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó tó bá a jà?” A fún un ní ẹnu láti fi sọ̀rọ̀ tí ó ju ẹnu rẹ̀ lọ, ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. A fún un ní àṣẹ fún oṣù mejilelogoji. Ó bá ya ẹnu, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ó ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun ati sí àgọ́ rẹ̀, ati sí àwọn tí wọ́n ń gbé ọ̀run. A fún un ní agbára láti gbógun ti àwọn eniyan Ọlọrun ati láti ṣẹgun wọn. A tún fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè ati oríṣìíríṣìí èdè ati gbogbo eniyan. Gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú ayé tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè bá ń júbà rẹ̀. Láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé ni a kò ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé Ọ̀dọ́ Aguntan tí a pa. Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́! Orin Àwọn Ọ̀kẹ́ Meje Ó Lé Ẹgbaaji (144,000) Eniyan. Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tí ó dúró lórí òkè Sioni, pẹlu àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a kọ orúkọ rẹ̀ ati orúkọ Baba rẹ̀ sí wọn níwájú. yóo mu ninu ògidì ọtí ibinu Ọlọrun, tí ó wà ninu ife ibinu rẹ̀. Olúwarẹ̀ yóo joró ninu iná àjóòkú níwájú àwọn angẹli mímọ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan. Èéfín iná oró àwọn tí wọ́n bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí wọ́n gba àmì orúkọ rẹ̀, yóo máa rú títí lae. Kò ní rọlẹ̀ tọ̀sán-tòru.” Èyí mú kí ó di dandan fún àwọn eniyan Ọlọrun, tí wọn ń pa àṣẹ Ọlọrun mọ́, tí wọ́n sì dúró ninu igbagbọ Jesu láti ní ìfaradà. Mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá tí ó sọ pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀! Àwọn òkú tí wọ́n kú ninu Oluwa láti àkókò yìí lọ ṣe oríire.”Ẹ̀mí jẹ́rìí sí i pé, “Bẹ́ẹ̀ ni dájúdájú, nítorí wọn yóo sinmi ninu làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn yóo máa tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.” Mo wá rí ìkùukùu funfun. Ẹnìkan tí ó dàbí ọmọ eniyan jókòó lórí ìkùukùu náà. Ó dé adé wúrà. Ó mú dòjé tí ó mú lọ́wọ́. Angẹli mìíràn jáde láti inú Tẹmpili wá, ó kígbe sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùukùu, pé, “Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún dòjé rẹ; àkókò ìkórè tó: ilé ayé ti tó kórè.” Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùukùu náà bá ti dòjé rẹ̀ bọ ilé ayé, ni ó bá kórè ayé. Angẹli mìíràn tún jáde wá láti inú Tẹmpili ní ọ̀run, tí òun náà tún mú dòjé mímú lọ́wọ́. Angẹli mìíràn wá ti ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ìrúbọ wá, òun ni ó ní àṣẹ lórí iná. Ó kígbe sí angẹli tí ó ní dòjé mímú pé, “Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún dòjé mímú rẹ. Kó èso àwọn igi eléso ilé ayé jọ, nítorí pé wọ́n ti pọ́n.” Ni angẹli tí ó ní dòjé náà bá ti dòjé rẹ̀ bọ inú ilé ayé, ó bá kó èso àjàrà ayé jọ, ó dà wọ́n sí ibi ìfúntí ibinu ńlá Ọlọrun. Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run bí ìró ọpọlọpọ omi ati bí ìgbà tí ààrá líle bá ń sán. Ohùn tí mo gbọ́ ni ti àwọn oníhapu tí wọn ń lu hapu wọn. Lẹ́yìn odi ìlú ni ìfúntí náà wà. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ èso ninu rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí yọ jáde láti inú ìfúntí náà. Jíjìn rẹ̀ mu ẹṣin dé ọrùn, ó sì gba ilẹ̀ lọ ní nǹkan bí igba ibùsọ̀. Wọ́n ń kọrin titun kan níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Kò sí ẹni tí ó lè mọ orin náà àfi àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a ti rà pada ninu ayé. Àwọn ni àwọn tí kò fi obinrin ba ara wọn jẹ́, nítorí wọn kò bá obinrin lòpọ̀ rí. Àwọn yìí ni wọ́n ń tẹ̀lé Ọ̀dọ́ Aguntan náà káàkiri ibi gbogbo tí ó bá ń lọ. Àwọn ni a ti rà pada láti inú ayé, wọ́n dàbí èso àkọ́so fún Ọlọrun ati fún Ọ̀dọ́ Aguntan. Ọ̀rọ̀ èké kankan kò sí ní ẹnu wọn. Kò sí àléébù ninu ìgbé-ayé wọn. Mo tún rí angẹli mìíràn tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run. Ó mú ìyìn rere ayérayé lọ́wọ́ láti kéde rẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ninu ayé, ninu gbogbo ẹ̀yà ati gbogbo orílẹ̀-èdè. Ó bá kígbe pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí àkókò ìdájọ́ rẹ̀ dé! Ẹ júbà ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, òkun ati gbogbo orísun omi.” Angẹli mìíràn tẹ̀lé ti àkọ́kọ́, ó ní, “Ó ti tú! Babiloni ìlú ńlá nnì ti tú! Ìlú tí ó fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní ọtí àgbèrè rẹ̀ mu, tí ó mú ibinu Ọlọrun wá, ó ti tú!” Angẹli kẹta wá tẹ̀lé wọn. Ó kígbe pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí ó gba àmì rẹ̀ siwaju rẹ̀ tabi sí ọwọ́ rẹ̀, Àwọn Angẹli tí Ó Mú Àjàkálẹ̀ Àrùn Ìkẹyìn Wá. Mo tún rí ohun abàmì mìíràn ní ọ̀run, ohun ńlá ati ohun ìyanu: àwọn angẹli meje tí àjàkálẹ̀ àrùn meje ti ìkẹyìn wà ní ìkáwọ́ wọn, nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibinu Ọlọrun wá sí òpin. Mo tún rí ohun tí ó dàbí òkun dígí tí iná wà ninu rẹ̀. Àwọn kan dúró lẹ́bàá òkun dígí náà, àwọn tí wọ́n ti ṣẹgun ẹranko náà ati ère rẹ̀, ati iye orúkọ rẹ̀. Wọ́n mú hapu Ọlọrun lọ́wọ́, wọ́n ń kọ orin Mose iranṣẹ Ọlọrun ati orin Ọ̀dọ́ Aguntan náà pé,“Iṣẹ́ ńlá ati iṣẹ́ ìyanu ni iṣẹ́ rẹ,Oluwa, Ọlọrun Olodumare.Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ,Ọba àwọn orílẹ̀-èdè. Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, Oluwa?Ta ni kò ní fi ògo fún orúkọ rẹ?Nítorí ìwọ nìkan ni ó pé,nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá,wọn yóo júbà níwájú rẹ,nítorí òdodo rẹ farahàn gbangba.” Lẹ́yìn èyí mo tún rí Tẹmpili tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run. Àgọ́-Ẹ̀rí wà ninu rẹ̀. Àwọn angẹli meje tí wọ́n ní àjàkálẹ̀ àrùn meje níkàáwọ́ jáde láti inú Tẹmpili náà wá, wọ́n wọ aṣọ funfun tí ó ń tàn bí ìmọ́lẹ̀. Wúrà ni wọ́n fi ṣe ìgbàyà wọn. Ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè náà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje náà ní àwo wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan, àwọn àwo wúrà yìí kún fún ibinu Ọlọrun, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae. Inú Tẹmpili wá kún fún èéfín ògo Ọlọrun ati ti agbára rẹ̀. Kò sí ẹni tí ó lè wọ inú Tẹmpili títí tí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn meje ti àwọn angẹli meje náà fi parí. Àwọn Àwo tí Ó Kún fún Ibinu Ọlọrun. Mo gbọ́ ohùn líle kan láti inú Tẹmpili tí ó sọ fún àwọn angẹli meje náà pé, “Ẹ lọ da àwọn àwo meje tí ó kún fún ibinu Ọlọrun sinu ayé.” Angẹli karun-un da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà, ó bá sọ ìjọba rẹ̀ di òkùnkùn. Àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí gé ara wọn láhọ́n jẹ nítorí ìrora wọn, wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun ọ̀run nítorí ìrora wọn ati nítorí egbò ara wọn, dípò kí wọ́n ronupiwada fún ohun tí wọ́n ti ṣe. Angẹli kẹfa da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sórí odò ńlá tí wọn ń pè ní Yufurate, ni omi rẹ̀ bá gbẹ láti fi ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ọba tí ń bọ̀ láti ìhà ìlà oòrùn. Mo wá rí àwọn ẹ̀mí burúkú mẹta kan, wọ́n dàbí ọ̀pọ̀lọ́ ní ẹnu Ẹranko Ewèlè náà, ati ní ẹnu wolii èké náà. Ẹ̀mí Èṣù ni àwọn ẹ̀mí náà, wọ́n sì lè ṣe ohun abàmì. Wọ́n jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, láti kó wọn jọ fún ogun ní ọjọ́ ńlá ti Ọlọrun alágbára jùlọ. “Bí olè ni mò ń bọ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣọ́nà ṣe oríire, tí olúwarẹ̀ wọ aṣọ rẹ̀, kí ó má baà sí ní ìhòòhò, kí ojú má baà tì í níwájú àwọn eniyan.” Ó bá kó àwọn ọba wọnyi jọ sí ibìkan tí ń jẹ́ Amagedoni ní èdè Heberu. Angẹli keje da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu afẹ́fẹ́. Ẹnìkan bá fi ohùn líle sọ̀rọ̀ láti ibi ìtẹ́ tí ó wà ninu Tẹmpili, ó ní, “Ó ti parí!” Ni mànàmáná bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ, ààrá ń sán, ilẹ̀ ń mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí irú rẹ̀ rí láti ìgbà tí eniyan ti dé orí ilẹ̀ ayé. Ìlú ńlá náà bá pín sí mẹta. Gbogbo ìlú àwọn orílẹ̀-èdè bá tú. Babiloni ìlú ńlá náà kò bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọrun, Ọlọrun jẹ́ kí ó mu ninu ìkorò ibinu rẹ̀. Angẹli kinni lọ, ó bá da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu ayé. Ni egbò rírà tí ń rùn bá dà bo àwọn tí wọ́n ní àmì ẹranko náà ní ara, tí wọ́n sì ń júbà ère rẹ̀. Omi bo gbogbo àwọn erékùṣù, a kò sì rí ẹyọ òkè kan mọ́. Yìnyín ńláńlá tí ó tóbi tó ọlọ ata wá bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ lu eniyan láti ojú ọ̀run. Àwọn eniyan wá ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí ìparun tí yìnyín yìí ń fà, nítorí ó ń ṣe ọpọlọpọ ijamba. Angẹli keji da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu òkun, ni òkun bá di ẹ̀jẹ̀, bí ẹ̀jẹ̀ ara òkú, gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí tí ó wà ninu òkun sì kú. Angẹli kẹta da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu odò ati sinu ìsun omi, ó bá di ẹ̀jẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn angẹli tí omi wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ tí ó sọ pé, “Olódodo ni ọ́ fún ìdájọ́ rẹ wọnyi, ìwọ tí ó wà, tí ó ti wà, ìwọ Ẹni Mímọ́! Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan rẹ ati àwọn wolii rẹ sílẹ̀, nítorí náà o fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu. Ohun tí ó yẹ wọ́n ni o fún wọn!” Mo bá gbọ́ tí pẹpẹ ìrúbọ wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, Ọlọrun, Olodumare, òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ.” Angẹli kẹrin da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ nù sórí oòrùn, a bá fún un lágbára láti máa jó eniyan bí iná. Oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí jó àwọn eniyan bí iná ńlá, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun tí ó ní àṣẹ lórí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn wọnyi, dípò kí wọ́n ronupiwada, kí wọ́n fi ògo fún un. Babiloni Ìlú Ńlá, Gbajúmọ̀ Àgbèrè. Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí wọ́n ní àwo meje náà tọ̀ mí wá, ó ní, “Wá kí n fi ìdájọ́ tí ń bọ̀ sórí gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà hàn ọ́, ìlú tí a kọ́ sójú ọpọlọpọ omi. Marun-un ninu wọn ti kú. Ọ̀kan wà lórí oyè nisinsinyii. Ọ̀kan yòókù kò ì tíì jẹ. Nígbà tí ó bá jọba, àkókò díẹ̀ ni yóo ṣe lórí oyè. Ẹranko tí ó ti wà láàyè rí, tí kò sí mọ́, ni ẹkẹjọ, ṣugbọn ó wà ninu àwọn meje tí ń lọ sinu ègbé. “Àwọn ìwo mẹ́wàá tí o rí jẹ́ ọba mẹ́wàá. Ṣugbọn wọn kò ì tíì joyè. Wọn óo gba àṣẹ fún wakati kan, àwọn ati ẹranko náà ni yóo jọ lo àṣẹ náà. Ète kanṣoṣo ni wọ́n ní. Wọn yóo fi agbára wọn ati àṣẹ wọn fún ẹranko náà. Wọn yóo bá Ọ̀dọ́ Aguntan náà jagun, ṣugbọn Ọ̀dọ́ Aguntan náà yóo ṣẹgun wọn nítorí pé òun ni Oluwa àwọn oluwa ati Ọba àwọn ọba. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu Ọ̀dọ́ Aguntan náà ninu ìjà ati ìṣẹ́gun náà ni àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí a pè, tí a sì yàn.” Ó tún wí fún mi pé, “Àwọn omi tí o rí níbi tí aṣẹ́wó náà ti jókòó ni àwọn eniyan ati gbogbo orílẹ̀-èdè. Nígbà tí ó bá yá, àwọn ìwo mẹ́wàá tí o rí yìí ati ẹranko náà, yóo kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn óo tú u sí ìhòòhò, wọn óo bá fi í sílẹ̀ ní ahoro. Wọn óo jẹ ẹran-ara rẹ̀, wọn óo bá dá iná sun ún títí yóo fi jóná ráúráú. Nítorí Ọlọrun fi sí ọkàn wọn láti ní ète kan náà, pé àwọn yóo fi ìjọba àwọn fún ẹranko náà títí gbogbo ohun tí Ọlọrun ti sọ yóo fi ṣẹ. “Obinrin tí o rí ni ìlú ńlá náà tí ó ń pàṣẹ lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.” Àwọn ọba ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn tí ń gbé inú ayé ti mu ninu ọtí àgbèrè rẹ̀.” Ẹ̀mí gbé mi, ni angẹli yìí bá gbé mi lọ sinu aṣálẹ̀. Níbẹ̀ ni mo ti rí obinrin tí ó gun ẹranko pupa kan, tí àwọn orúkọ àfojúdi kún ara rẹ̀. Ẹranko náà ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá. Aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa ni obinrin náà wọ̀. Ó fi ọ̀ṣọ́ wúrà sára pẹlu oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀ olówó iyebíye. Ó mú ife wúrà lọ́wọ́, ife yìí kún fún ẹ̀gbin ati ohun ìbàjẹ́ àgbèrè rẹ̀. Orúkọ àṣírí kan wà níwájú rẹ̀, ìtumọ̀ rẹ̀ ni: “Babiloni ìlú ńlá, ìyá àwọn àgbèrè ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin ayé.” Mo wá rí obinrin náà tí ó ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan Ọlọrun ní àmuyó, pẹlu ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu.Ìyanu ńlá ni ó jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí obinrin náà. Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni ó yà ọ́ lẹ́nu? N óo sọ àṣírí obinrin náà fún ọ ati ti ẹranko tí ó gùn, tí ó ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá. Ẹranko tí o rí yìí ti wà láàyè nígbà kan rí, ṣugbọn kò sí láàyè mọ́ nisinsinyii. Ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò, tí yóo gòkè wá láti inú ọ̀gbun jíjìn, tí yóo wá lọ sí ibi ègbé. Nígbà tí wọ́n bá rí ẹranko náà ẹnu yóo ya àwọn tí ó ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, nítorí ó ti wà láàyè, ṣugbọn kò sí láàyè nisinsinyii, ṣugbọn yóo tún pada yè. “Ọ̀rọ̀ yìí gba ọgbọ́n. Orí meje tí ẹranko náà ní jẹ́ òkè meje tí obinrin náà jókòó lé lórí. Wọ́n tún jẹ́ ọba meje. Babiloni tú. Lẹ́yìn èyí mo tún rí angẹli tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ní àṣẹ ńlá. Gbogbo ayé mọ́lẹ̀ nítorí ẹwà ògo rẹ̀. Wọn óo dúró ní òkèèrè nítorí ẹ̀rù tí yóo máa bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀. Wọn óo sọ pé,“Ó ṣe! Ó ṣe fún ọ! Ìlú ńlá,Babiloni ìlú alágbára!Nítorí ní wakati kan ni ìparun dé bá ọ.” Àwọn oníṣòwò ayé yóo sunkún, wọn yóo ṣọ̀fọ̀ lé e lórí, nítorí wọn kò rí ẹni ra ọjà wọn mọ́; àwọn nǹkan bíi: Wúrà, fadaka, òkúta iyebíye, oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀, aṣọ funfun ati àlàárì, ati sányán ati aṣọ pupa; oríṣìíríṣìí pákó, ati àwọn ohun èèlò tí a fi eyín erin, igi iyebíye, idẹ, irin, ati òkúta ṣe; oríṣìíríṣìí òróró ìkunra, turari ati òjíá, ọtí, òróró olifi, ọkà, ati àgbàdo, ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun, ẹrú, àní ẹ̀mí eniyan. Wọ́n ní, “Èso tí o fẹ́ràn kò sí mọ́, gbogbo ìgbé-ayé fàájì ati ti ìdẹ̀ra ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ, o kò tún ní rí irú rẹ̀ mọ́.” Àwọn oníṣòwò wọnyi, tí wọ́n ti di olówó ninu rẹ̀ yóo dúró ní òkèèrè nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀, wọn óo máa sunkún, wọn óo máa ṣọ̀fọ̀. Wọn óo máa wí pé, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà! Ìlú tí ó wọ aṣọ funfun, ati aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa. Ìlú tí wúrà pọ̀ níbẹ̀ ati òkúta iyebíye ati ìlẹ̀kẹ̀! Ní wakati kan péré ni gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ run!”Nígbà náà ni gbogbo ọ̀gá àwọn awakọ̀ ojú omi, ati gbogbo àwọn tí ó ń wọ ọkọ̀ ati àwọn atukọ̀ ati àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ ojú omi òkun lọ dúró ní òkèèrè. Wọ́n ń kígbe sókè nígbà tí wọ́n rí èéfín iná tí ń jó ìlú náà. Wọ́n wá ń sọ pé, “Ìlú wo ni ó dàbí ìlú ńlá yìí?” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bu yẹ̀ẹ̀pẹ̀ sórí ara wọn, wọ́n ń sunkún, wọ́n ń ṣọ̀fọ̀. Wọ́n ní, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà, níbi tí gbogbo àwọn tí wọn ní ọkọ̀ lójú òkun ti di ọlọ́rọ̀ nípa ọrọ̀ rẹ̀, nítorí ní wakati kan ó ti di ahoro! Ó wá kígbe pé, “Ó tú! Babiloni ìlú ńlá tú! Ó wá di ibi tí àwọn àǹjọ̀nnú ń gbé, tí ẹ̀mí Èṣù oríṣìíríṣìí ń pààrà, tí oríṣìíríṣìí ẹyẹkẹ́yẹ ń kiri. Ọ̀run, yọ̀ lórí rẹ̀! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin eniyan Ọlọrun, ẹ̀yin aposteli, ati ẹ̀yin wolii, nítorí Ọlọrun ti ṣe ìdájọ́ fún un bí òun náà ti ṣe fún yín!” Ọ̀kan ninu àwọn angẹli alágbára bá gbé òkúta tí ó tóbi bí ọlọ ògì, ó jù ú sinu òkun, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni a óo fi tagbára-tagbára sọ Babiloni ìlú ńlá náà mọ́lẹ̀ tí a kò ní rí i mọ́. A kò tún ní gbọ́ ohùn fèrè ati ti àwọn olórin tabi ti ohùn ìlù ati ti ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ninu rẹ mọ́. A kò ní tún rí àwọn oníṣọ̀nà fún iṣẹ́ ọnà kan ninu rẹ mọ́. A kò ní gbọ́ ìró ọlọ ninu rẹ mọ́. Iná àtùpà kan kò ní tàn ninu rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ti iyawo ninu rẹ mọ́. Nígbà kan rí àwọn oníṣòwò rẹ ni àwọn gbajúmọ̀ ninu ayé. O fi ìwà àjẹ́ tan gbogbo orílẹ̀-èdè jẹ.” Ninu rẹ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wolii ati ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan Ọlọrun, ati gbogbo àwọn ẹni tí wọ́n pa lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti mu àmuyó ninu ọtí àgbèrè rẹ̀, ọtí tí ó fa ibinu Ọlọrun. Àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn oníṣòwò ilẹ̀ ayé ti di olówó nípa ìwà jayéjayé rẹ̀.” Mo tún gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run tí ó sọ pé,“Ẹ jáde kúrò ninu rẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi,kí ẹ má baà ní ìpín ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,kí ẹ má baà fara gbá ninu ìjìyà rẹ̀. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga dé ọ̀run,Ọlọrun kò gbàgbé àìṣedéédé rẹ̀. Ṣe fún un bí òun náà ti ṣe fún eniyan.Gbẹ̀san lára rẹ̀ ní ìlọ́po meji ìwà rẹ̀.Ife tí ó fi ń bu ọtí fún eniyan nikí o fi bu ọtí tí ó le ní ìlọ́po meji fún òun alára. Bí ó ti ṣe ń jẹ ọlá,tí ó ń jẹ ayé tẹ́lẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kí o fún un ní ìrora ati ìbànújẹ́.Ó ń sọ ní ọkàn rẹ̀ pé,‘Ọba orí ìtẹ́ ni mí,èmi kì í ṣe opó,ojú mi kò ní rí ìbànújẹ́.’ Nítorí èyí, ní ọjọ́ kan náà ni oríṣìíríṣìí òfò yóo dé bá a,ati àjàkálẹ̀ àrùn, ati ọ̀fọ̀, ati ìyàn.Iná yóo tún jó o ní àjórun,nítorí alágbára ni Oluwa Ọlọrun tí ó ti ń ṣe ìdájọ́ fún un.” Àwọn ọba ayé ati àwọn tí wọ́n ti bá a ṣe àgbèrè, tí wọ́n ti ń bá a jayé yóo sunkún, wọn óo ṣọ̀fọ̀ lé e lórí nígbà tí wọ́n bá rí èéfín iná tí ń jó o. Àsè Igbeyawo ti Ọ̀dọ́ Aguntan. Lẹ́yìn èyí mo gbọ́ ohùn kan bí igbe ọ̀pọ̀ eniyan ní ọ̀run, tí ń sọ pé, “Haleluya! Ìgbàlà ati ògo ati agbára ni ti Ọlọrun wa. Ni mo bá dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, mo júbà rẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ bí ìwọ ati àwọn arakunrin rẹ, tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu, ni èmi náà. Ọlọrun ni kí o júbà.”Nítorí ẹ̀mí tí ó mú kí eniyan jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu ni ẹ̀mí tí ó wà ninu wolii. Mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀. Mo wá rí ẹṣin funfun kan. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Olódodo ati Olóòótọ́, nítorí pẹlu òdodo ni ó ń ṣe ìdájọ́, tí ó sì ń jagun. Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná. Ó dé adé pupọ tí a kọ orúkọ sí, orúkọ tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀ àfi òun alára. Ó wọ ẹ̀wù tí a rẹ sinu ẹ̀jẹ̀. Orúkọ tí à ń pè é ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ọmọ-ogun ọ̀run ń tẹ̀lé e, wọ́n gun ẹṣin funfun. Aṣọ tí wọ́n wọ̀ funfun, ó sì mọ́. Idà mímú yọ jáde ní ẹnu rẹ̀, tí yóo fi ṣẹgun àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí òun ni yóo jọba lórí wọn pẹlu ọ̀pá irin. Òun ni yóo pọn ọtí ibinu ati ti ẹ̀san Ọlọrun Olodumare. A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.” Mo tún rí angẹli kan tí ó dúró ninu oòrùn, ó kígbe sí àwọn ẹyẹ tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run pé, “Ẹ wá péjọ sí ibi àsè ńlá Ọlọrun, kí ẹ lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba ati ti àwọn ọ̀gágun, ati ti àwọn alágbára, ati ẹran ẹṣin ati ti àwọn tí wọ́n gùn wọ́n, ati ẹran-ara àwọn òmìnira ati ti ẹrú, ti àwọn mẹ̀kúnnù ati ti àwọn ọlọ́lá.” Mo wá rí ẹranko náà ati àwọn ọba ilé ayé ati àwọn ọmọ-ogun wọn. Wọ́n péjọ láti bá ẹni tí ó gun ẹṣin funfun náà ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jagun. Òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí ó ti dájọ́ fún gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà, tí ó fi àgbèrè rẹ̀ ba ayé jẹ́. Ó ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀ lára rẹ̀.” A mú ẹranko náà lẹ́rú, pẹlu wolii èké tí ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì níwájú rẹ̀, tí ó ti tan àwọn tí wọ́n gba àmì ẹranko náà jẹ, ati àwọn tí wọ́n júbà ère rẹ̀. A wá gbé àwọn mejeeji láàyè, a sọ wọ́n sinu adágún iná tí a fi imí-ọjọ́ dá. Wọ́n fi idà tí ó wà lẹ́nu ẹni tí ó gun ẹṣin funfun pa àwọn yòókù. Gbogbo àwọn ẹyẹ bá ń jẹ ẹran-ara wọn ní àjẹrankùn. Wọ́n tún wí lẹẹkeji pé, “Haleluya! Èéfín rẹ̀ ń gòkè lae ati laelae.” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun tí ó jókòó lórí ìtẹ́. Wọ́n ní, “Amin! Haleluya!” Ẹnìkan fọhùn láti orí ìtẹ́ náà, ó ní, “Ẹ yin Ọlọrun wa, gbogbo ẹ̀yin ìran rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù rẹ̀, ẹ̀yin mẹ̀kúnnù ati ẹ̀yin eniyan pataki.” Mo tún gbọ́ ohùn kan bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, ati bí ìró ọpọlọpọ omi, ati bí sísán ààrá líle, ohùn náà sọ pé, “Haleluya! Nítorí Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare jọba. Ẹ jẹ́ kí á yọ̀, kí inú wa dùn, ẹ jẹ́ kí á fi ògo fún un, nítorí ó tó àkókò igbeyawo Ọ̀dọ́ Aguntan náà. Iyawo rẹ̀ sì ti ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ dè é. A fún un ní aṣọ funfun tí ń dán, tí ó sì mọ́. Aṣọ funfun náà ni iṣẹ́ òdodo àwọn eniyan Ọlọrun.” Ó sọ fún mi pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀: àwọn tí a pè sí àsè igbeyawo ti Ọ̀dọ́ Aguntan náà ṣe oríire.” Ó tún sọ fún mi pé, “Òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ọ̀rọ̀ wọnyi.” Iṣẹ́ sí Ìjọ Efesu. “Kọ ìwé yìí sí òjíṣẹ́ ìjọ Efesu:“Ẹni tí ó di ìràwọ̀ meje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, tí ó ń rìn láàrin àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà meje wí báyìí pé, Má bẹ̀rù ohunkohun tí ò ń bọ̀ wá jìyà. Èṣù yóo gbé ẹlòmíràn ninu yín jù sinu ẹ̀wọ̀n láti fi dán yín wò. Fún ọjọ́ mẹ́wàá ẹ óo ní ìṣòro pupọ. Ṣugbọn jẹ́ olóòótọ́ dé ojú ikú, Èmi yóo sì fún ọ ní adé ìyè. “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.“Ẹni tí ó bá ṣẹgun kò ní kú ikú keji. “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Pẹgamu pé:“Ẹni tí ó ní idà olójú meji tí ó mú ní: Mo mọ ibi tí ò ń gbé, ibẹ̀ ni Satani tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí. Sibẹ o di orúkọ mi mú, o kò bọ́hùn ninu igbagbọ ní ọjọ́ tí wọ́n pa Antipasi ẹlẹ́rìí òtítọ́ mi ní ìlú yín níbi tí Satani fi ṣe ilé. Ṣugbọn mo ní àwọn nǹkan díẹ̀ wí sí ọ. O ní àwọn kan láàrin ìjọ tí wọ́n gba ẹ̀kọ́ Balaamu, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti fi ohun ìkọsẹ̀ siwaju àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n fi ń jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà, tí wọ́n tún ń ṣe àgbèrè. O tún ní àwọn kan tí àwọn náà gba ẹ̀kọ́ àwọn Nikolaiti. Nítorí náà, ronupiwada. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ n óo wá láìpẹ́, n óo sì fi idà tí ó wà lẹ́nu mi bá wọn jà. “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.“Ẹni tí ó bá ṣẹgun, Èmi óo fún un ní mana tí a ti fi pamọ́. N óo tún fún un ní òkúta funfun kan tí a ti kọ orúkọ titun sí lára. Ẹnikẹ́ni kò mọ orúkọ titun yìí àfi ẹni tí ó bá gba òkúta náà. “Kọ ìwé yìí sí ìjọ Tiatira pé:“Ọmọ Ọlọrun, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọwọ́ iná, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dán bí idẹ. Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ ìfẹ́ rẹ ati igbagbọ rẹ, mo mọ iṣẹ́ rere tí ò ń ṣe ati ìfaradà rẹ. Iṣẹ́ rẹ ti ìkẹyìn tilẹ̀ dára ju ti àkọ́kọ́ lọ. Mo mọ iṣẹ́ rẹ, ati làálàá rẹ, ati ìfaradà rẹ. Mo mọ̀ pé o kò jẹ́ gba àwọn eniyan burúkú mọ́ra. O ti dán àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọn kì í ṣe aposteli wò, o ti rí i pé òpùrọ́ ni wọ́n. Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O gba obinrin tí wọn ń pè ní Jesebẹli láàyè. Ó ń pe ara rẹ̀ ní aríran, ó ń tan àwọn iranṣẹ mi jẹ, ó ń kọ́ wọn láti ṣe àgbèrè ati láti jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà. Mo fún un ní àkókò kí ó ronupiwada, ṣugbọn kò fẹ́ ronupiwada kúrò ninu ìwà àgbèrè rẹ̀. N óo dá a dùbúlẹ̀ àìsàn. Ìṣòro pupọ ni yóo bá àwọn tí wọ́n bá bá a ṣe àgbèrè, àfi bí wọ́n bá rí i pé iṣẹ́ burúkú ni ó ń ṣe, tí wọn kò sì bá a lọ́wọ́ ninu rẹ̀ mọ́. N óo fi ikú pa àwọn ọmọ rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjọ ni yóo wá mọ̀ pé Èmi ni Èmi máa ń wádìí ọkàn ati èrò ẹ̀dá, n óo sì fi èrè fún olukuluku yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. “Ṣugbọn ẹ̀yin yòókù ní Tiatira, ẹ̀yin tí ẹ kò gba ẹ̀kọ́ obinrin yìí, ẹ̀yin tí ẹ kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí wọn ń pè ní ohun ìjìnlẹ̀ Satani, n kò ní di ẹrù mìíràn rù yín mọ́. Ṣugbọn ṣá, ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin títí n óo fi dé. Ẹni tí ó bá ṣẹgun, tí ó forí tì í, tí ó ń ṣe iṣẹ́ mi títí dé òpin, òun ni n óo fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, ọ̀pá irin ni yóo fi jọba lórí wọn, bí ìkòkò amọ̀ ni yóo fọ́ wọn túútúú. Irú àṣẹ tí mo gbà lọ́dọ̀ Baba mi ni n óo fún un. N óo tún fún un ní ìràwọ̀ òwúrọ̀. “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. O ní ìfaradà. O ti farada ìyà nítorí orúkọ mi, o kò sì jẹ́ kí àárẹ̀ mú ọ. Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O ti kọ ìfẹ́ tí o ní nígbà tí o kọ́kọ́ gbàgbọ́ sílẹ̀. Nítorí náà, ranti bí o ti ga tó tẹ́lẹ̀ kí o tó ṣubú; ronupiwada, kí o sì ṣiṣẹ́ bíi ti àkọ́kọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, bí o kò bá ronupiwada, n óo mú ọ̀pá fìtílà rẹ kúrò ní ipò rẹ̀. Ṣugbọn ò ń ṣe kinní kan tí ó dára: o kórìíra iṣẹ́ àwọn Nikolaiti, tí èmi náà kórìíra. “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.“Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fún ní àṣẹ láti jẹ ninu èso igi ìyè tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun. “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Simana:“Báyìí ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó kú, tí ó tún wà láàyè: Mo mọ̀ pé o ní ìṣòro; ati pé o ṣe aláìní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́rọ̀ ni ọ́ ní ọ̀nà mìíràn. Mo mọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní Juu ń sọ, àwọn tí kì í sì í ṣe Juu; tí ó jẹ́ pé ilé ìpàdé Satani ni wọ́n. Ìjọba Ẹgbẹrun Ọdún. Mo wá rí angẹli kan tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó mú kọ́kọ́rọ́ kànga tí ó jìn pupọ náà lọ́wọ́ ati ẹ̀wọ̀n gígùn. A bá ju Èṣù tí ó ń tàn wọ́n jẹ sinu adágún iná tí a fi imí-ọjọ́ dá, níbi tí ẹranko náà ati wolii èké náà wà, tí wọn yóo máa joró tọ̀sán-tòru lae ati laelae. Mo wá rí ìtẹ́ funfun ńlá kan ati ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀. Ayé ati ọ̀run sálọ fún un, a kò rí ààyè fún wọn mọ́. Mo rí òkú àwọn ọlọ́lá ati ti àwọn mẹ̀kúnnù, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn ìwé àkọsílẹ̀ wà ní ṣíṣí. Ìwé mìíràn tún wà ní ṣíṣí, tí orúkọ àwọn alààyè wà ninu rẹ̀. A wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ àwọn òkú gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn tí ó wà ninu àwọn ìwé àkọsílẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n kú sinu òkun tún jáde sókè. Gbogbo òkú tí ó wà níkàáwọ́ ikú ati àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú ni wọ́n tún jáde. A wá ṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. Ni a bá ju ikú ati ipò òkú sinu adágún iná. Adágún iná yìí ni ikú keji. Ẹnikẹ́ni tí kò bá sí orúkọ rẹ̀ ninu ìwé ìyè, a óo sọ ọ́ sinu adágún iná. Ó bá ki Ẹranko Ewèlè náà mọ́lẹ̀, ejò àtijọ́ náà tíí ṣe Èṣù tabi Satani, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é fún ẹgbẹrun ọdún. Ó bá jù ú sinu kànga tí ó jìn pupọ náà, ó pa ìdérí rẹ̀ dé mọ́ ọn lórí. Ó bá fi èdìdì dì í kí ó má baà tan àwọn eniyan jẹ mọ́ títí ẹgbẹrun ọdún yóo fi parí. Lẹ́yìn náà, a óo dá a sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí eniyan jókòó lórí wọn. A fún àwọn eniyan wọnyi láṣẹ láti ṣe ìdájọ́. Àwọn ni ọkàn àwọn tí wọ́n ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jesu ati nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ni wọ́n kò júbà ẹranko náà tabi ère rẹ̀, wọn kò sì gba àmì rẹ̀ siwaju wọn tabi sí ọwọ́ wọn. Wọ́n tún wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹlu Kristi fún ẹgbẹrun ọdún. Àwọn òkú yòókù kò jí dìde títí òpin ẹgbẹrun ọdún. Èyí ni ajinde kinni. Àwọn eniyan Ọlọrun tí ó bá ní ìpín ninu ajinde kinni ṣe oríire. Ikú keji kò ní ní àṣẹ lórí wọn. Wọn óo jẹ́ alufaa Ọlọrun ati ti Kristi, wọn óo sì jọba pẹlu rẹ̀ fún ẹgbẹrun ọdún. Nígbà tí ẹgbẹrun ọdún bá parí a óo tú Satani sílẹ̀ ninu ẹ̀wọ̀n tí ó ti wà. Yóo wá tún jáde lọ láti máa tan àwọn eniyan jẹ ní igun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé. Yóo kó gbogbo eniyan Gogu ati Magogu jọ láti jagun, wọn óo pọ̀ bí iyanrìn etí òkun. Wọ́n gba gbogbo ìbú ilẹ̀ ayé, wọ́n wá yí àwọn eniyan Ọlọrun ká ati ìlú tí Ọlọrun fẹ́ràn. Ni iná bá sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, ó bá jó wọn run patapata. Ọ̀run Titun ati Ayé Titun. Mo rí ọ̀run titun ati ayé titun, ayé ti àkọ́kọ́ ti kọjá lọ. Òkun kò sì sí mọ́. Ó bá gbé mi ninu ẹ̀mí lọ sí orí òkè ńlá kan tí ó ga, ó fi Jerusalẹmu ìlú mímọ́ náà hàn mí, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Ògo Ọlọrun ń tàn lára rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye. Ẹwà rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye tí ó mọ́lẹ̀ gaara. Odi ìlú náà nípọn, ó sì ga. Ó ní ìlẹ̀kùn mejila, àwọn angẹli mejila wà níbi àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà. A kọ àwọn orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli mejila sí ara àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà. Ìlẹ̀kùn mẹta wà ní ìhà ìlà oòrùn, mẹta wà ní ìhà àríwá, mẹta wà ni ìhà gúsù, mẹta wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. Odi ìlú náà ní ìpìlẹ̀ mejila. Orúkọ mejila ti àwọn aposteli mejila ti Ọ̀dọ́ Aguntan wà lára wọn. Ẹni tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ mú ọ̀pá ìwọnlẹ̀ wúrà lọ́wọ́ láti fi wọn ìlú náà ati àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, ati odi rẹ̀. Igun mẹrẹẹrin ìlú náà dọ́gba, bákan náà ni gígùn rẹ̀ ati ìbú rẹ̀. Ó fi ọ̀pá ìwọnlẹ̀ náà wọn ìlú náà. Bákan náà ni gígùn rẹ̀, ati ìbú rẹ̀, ati gíga rẹ̀. Ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹjọ (1500) ibùsọ̀. Ó wá wọn odi rẹ̀, ó ga tó igba ẹsẹ̀ ó lé ogún (220) gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n eniyan tí angẹli náà ń lò. Òkúta iyebíye ni wọ́n fi mọ odi náà. Wúrà ni gbogbo ìlú náà tí ó mọ́ gaara bíi dígí. Òkúta iyebíye oríṣìíríṣìí ni wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ odi ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ kinni, òkúta iyebíye oríṣìí kan, ekeji oríṣìí mìíràn, ẹkẹta oríṣìí mìíràn, ẹkẹrin, bẹ́ẹ̀; Lẹ́yìn náà mo rí ìlú mímọ́ náà, Jerusalẹmu titun, tí ó ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sọ̀kalẹ̀ láti òkè wá. A ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ bí ìgbà tí a bá ṣe iyawo lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. ẹkarun-un, bẹ́ẹ̀; ẹkẹfa, bẹ́ẹ̀, ekeje bẹ́ẹ̀, ẹkẹjọ, bẹ́ẹ̀, ẹkẹsan-an, bẹ́ẹ̀, ẹkẹwaa, bẹ́ẹ̀, ikọkanla bẹ́ẹ̀, ekejila náà, bẹ́ẹ̀. Òkúta tí ó dàbí ìlẹ̀kẹ̀ ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn mejeejila ìlú náà; ẹyọ òkúta kọ̀ọ̀kan ni wọ́n fi gbẹ́ ìlẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan. Wúrà ni wọ́n yọ́ sí títì ìlú náà. Ó mọ́ gaara bíi dígí. N kò rí Tẹmpili ninu ìlú náà. Nítorí Oluwa Ọlọrun ati Ọ̀dọ́ Aguntan ni Tẹmpili ibẹ̀. Ìlú náà kò nílò ìmọ́lẹ̀ oòrùn tabi ti òṣùpá, nítorí pé ògo Ọlọrun ni ó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí i; Ọ̀dọ́ Aguntan ni àtùpà ibẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa rìn ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn ọba ilé-ayé yóo mú ọlá wọn wá sinu rẹ̀. Wọn kò ní ti àwọn ìlẹ̀kùn ìlú náà ní gbogbo ọ̀sán; òru kò sì ní sí níbẹ̀. Wọn yóo mú ẹwà ati ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sí inú rẹ̀. Ohun ìdọ̀tí kan kò ní wọ inú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá ń ṣe ohun ẹ̀gbin tabi èké kò ní wọ ibẹ̀. Àwọn tí a ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Aguntan nìkan ni yóo wọ ibẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn líle kan láti orí ìtẹ́ náà wá tí ó wí pé, “Ọlọrun pàgọ́ sí ààrin àwọn eniyan, yóo máa bá wọn gbé, wọn yóo jẹ́ eniyan rẹ̀, Ọlọrun pàápàá yóo wà pẹlu wọn; yóo nu gbogbo omijé nù ní ojú wọn. Kò ní sí ikú mọ́, tabi ọ̀fọ̀ tabi ẹkún tabi ìrora. Nítorí àwọn ohun ti àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà sọ pé, “Mò ń sọ ohun gbogbo di titun.” Ó ní, “Kọ ọ́ sílẹ̀, nítorí òdodo ọ̀rọ̀ ati òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí.” Ó ní, “Ó parí! Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin. N óo fún ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ ní omi mu láti inú kànga omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni yóo jogún nǹkan wọnyi. N óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ̀, òun náà yóo sì máa jẹ́ ọmọ mi. Ṣugbọn àwọn ojo, àwọn alaigbagbọ, àwọn ẹlẹ́gbin, àwọn apànìyàn, àwọn àgbèrè, àwọn oṣó, àwọn abọ̀rìṣà, ati gbogbo àwọn èké ni yóo ní ìpín wọn ninu adágún iná tí ń jó, tí a fi imí-ọjọ́ dá. Èyí ni ikú keji.” Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí ó mú àwo meje lọ́wọ́, tí ìparun ìkẹyìn meje wà ninu wọn, ó wá bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní “Wá, n óo fi iyawo Ọ̀dọ́ Aguntan hàn ọ́.” Dídé Kristi. Ó wá fi odò omi ìyè hàn mí, tí ó mọ́ gaara bíi dígí. Ó ń ti ibi ìtẹ́ Ọlọrun ati Ọ̀dọ́ Aguntan ṣàn wá. Ó tún sọ fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí nítorí àkókò tí wọn yóo ṣẹ súnmọ́ tòsí. Ẹni tí ó bá ń hùwà burúkú, kí ó máa hùwà burúkú rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣe ohun èérí, kí ó máa ṣe ohun èérí rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó bá ń hùwà rere, kí ó máa hùwà rere rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun, kí ó máa ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun bọ̀.” “Mò ń bọ̀ ní kíá. Èrè mi sì wà lọ́wọ́ mi, tí n óo fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí. Èmi ni Alfa ati Omega, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.” Àwọn tí wọ́n bá fọ aṣọ wọn ṣe oríire. Wọn óo ní àṣẹ láti dé ibi igi ìyè, wọn óo sì gba ẹnu ọ̀nà wọ inú ìlú mímọ́ náà. Lóde ni àwọn ajá yóo wà ati àwọn oṣó ati àwọn àgbèrè, ati àwọn apànìyàn ati àwọn abọ̀rìṣà ati àwọn tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe èké. “Èmi Jesu ni mo rán angẹli mi láti jíṣẹ́ gbogbo nǹkan wọnyi fún ẹ̀yin ìjọ. Èmi gan-an ni gbòǹgbò ati ọmọ Dafidi. Èmi ni ìràwọ̀ òwúrọ̀.” Ẹ̀mí ati Iyawo ń wí pé, “Máa bọ̀!”Ẹni tí ó gbọ́ níláti sọ pé, “Máa bọ̀.”Ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ kí ó wá, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mu omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. Mò ń kìlọ̀ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá fi nǹkankan kún un, Ọlọrun yóo fi kún àwọn ìyà rẹ̀ tí a ti kọ sinu ìwé yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá mú nǹkankan kúrò ninu ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí, Ọlọrun yóo mú ìpín rẹ̀ kúrò lára igi ìyè ati kúrò ninu ìlú mímọ́ náà, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé yìí. Ó gba ààrin títì ìlú náà. Igi ìyè kan wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ òsì odò náà. Igi ìyè yìí ń so èso mejila, ọ̀kan ní oṣooṣù. Ewé igi náà wà fún ìwòsàn àwọn orílẹ̀-èdè. Ẹni tí ó jẹ́rìí sí nǹkan wọnyi sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, tètè máa bọ̀. Amin! Máa bọ̀, Oluwa Jesu.” Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu gbogbo yín. Kò ní sí ègún mọ́. Ìtẹ́ Ọlọrun ati ti Ọ̀dọ́ Aguntan yóo wà níbẹ̀. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo máa sìn ín. Wọn óo rí i lojukooju, orúkọ rẹ̀ yóo sì wà níwájú wọn. Kò ní sí òru mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní nílò ìmọ́lẹ̀ àtùpà tabi ìmọ́lẹ̀ oòrùn, nítorí Oluwa Ọlọrun wọn ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún wọn. Wọn yóo sì máa jọba lae ati laelae. Ó tún sọ fún mi pé, “Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Oluwa Ọlọrun tí ó mí sinu àwọn wolii rẹ̀ ni ó rán angẹli rẹ̀ pé kí ó fi àwọn ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn iranṣẹ rẹ̀.” “Mò ń bọ̀ kíákíá. Ẹni tí ó bá pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́ ṣe oríire.” Èmi Johanu ni mo gbọ́ nǹkan wọnyi, tí mo sì rí wọn. Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí wọn, mo dojúbolẹ̀ níwájú angẹli tí ó fi wọ́n hàn mí. Ṣugbọn ó sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi náà ati ti àwọn wolii, arakunrin rẹ, ati ti àwọn tí wọ́n ti pa àwọn ọ̀rọ̀ ìwé yìí mọ́. Ọlọrun ni kí o júbà.” Iṣẹ́ sí Ìjọ Sadi. “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Sadi:“Ẹni tí ó ní Ẹ̀mí Ọlọrun meje ati ìràwọ̀ meje ní: Mo mọ iṣẹ́ rẹ. O kàn ní orúkọ pé o wà láàyè ni, òkú ni ọ́! Nítorí o ti fi ìfaradà pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Èmi náà yóo pa ọ́ mọ́ ní àkókò ìdánwò tí ń bọ̀ wá bá ayé, nígbà tí a óo dán gbogbo àwọn tí ó ń gbé inú ayé wò. Mò ń bọ̀ kíákíá. Di ohun tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má baà gba adé rẹ. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fi ṣe òpó ninu Tẹmpili Ọlọrun mi. Kò ní kúrò níbẹ̀ mọ́. N óo wá kọ orúkọ Ọlọrun mi ati orúkọ mi titun sí i lára, ati ti Jerusalẹmu titun, ìlú Ọlọrun mi, tí ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun mi. “Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá àwọn ìjọ sọ. “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Laodikia pé:“Ẹni tí ń jẹ́ Amin, olóòótọ́ ati ẹlẹ́rìí òdodo, alákòóso ẹ̀dá Ọlọrun ní Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ̀ pé o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù. Ninu kí o gbóná tabi kí o tutù, ó yẹ kí o ṣe ọ̀kan. Nítorí pé o lọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ lásán, o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù, n óo pọ̀ ọ́ jáde lẹ́nu mi. Nítorí ò ń sọ pé: Mo lówó, mo lọ́rọ̀. Kò sí ohun tí mo fẹ́ tí n kò ní. O kò mọ̀ pé akúṣẹ̀ẹ́ tí eniyan ń káàánú ni ọ́, òtòṣì afọ́jú tí ó wà ní ìhòòhò. Mo dá ọ nímọ̀ràn pé kí o ra wúrà tí wọ́n ti dà ninu iná lọ́wọ́ mi, kí o lè ní ọrọ̀, kí o ra aṣọ funfun kí o fi bora, kí ìtìjú ìhòòhò tí o wà má baà hàn, sì tún ra òògùn ojú, kí o fi sí ojú rẹ kí o lè ríran. Àwọn tí mo bá fẹ́ràn ni mò ń bá wí, àwọn ni mò ń tọ́ sọ́nà. Nítorí náà ní ìtara, kí o sì ronupiwada. Jí lójú oorun! Fún àwọn ohun tí ó ṣẹ́kù ní okun, nítorí àwọn náà ń kú lọ. Nítorí n kò rí iṣẹ́ kan tí o ṣe parí níwájú Ọlọrun mi. Wò ó! Mo dúró ní ẹnu ọ̀nà, mò ń kan ìlẹ̀kùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi, tí ó ṣílẹ̀kùn, n óo wọlé tọ̀ ọ́ lọ, n óo bá a jẹun, òun náà yóo sì bá mi jẹun. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo jẹ́ kí ó jókòó tì mí lórí ìtẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí Èmi náà ti ṣẹgun, tí mo jókòó ti baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀. “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá àwọn ìjọ sọ.” Nítorí náà, ranti ohun tí o ti gbà tí o sì ti gbọ́, ṣe é, kí o sì ronupiwada. Bí o kò bá jí lójú oorun, n óo dé bí olè, o kò sì ní mọ àkókò tí n óo dé bá ọ. Ṣugbọn o ní àwọn díẹ̀ ninu ìjọ Sadi tí wọn kò fi èérí ba aṣọ wọn jẹ́. Wọn yóo bá mi kẹ́gbẹ́ ninu aṣọ funfun nítorí wọ́n yẹ. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni a óo wọ̀ ní aṣọ funfun bẹ́ẹ̀. N kò ní pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè. N óo jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi ati níwájú àwọn angẹli rẹ̀. “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Filadẹfia pé:“Ẹni mímọ́ ati olóòótọ́ nì, ẹni tí kọ́kọ́rọ́ Dafidi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, tíí ṣí ìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè tì í, tíí sìí tìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí i, ó ní: Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Wò ó! Mo fi ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ siwaju rẹ, tí ẹnikẹ́ni kò lè tì. Mo mọ̀ pé agbára rẹ kéré, sibẹ o ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. O kò sẹ́ orúkọ mi. N óo fi àwọn kan láti inú ilé ìpàdé Satani lé ọ lọ́wọ́, àwọn òpùrọ́ tí wọn ń pe ara wọn ní Juu, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ṣe Juu. N óo ṣe é tí wọn yóo fi wá sọ́dọ̀ rẹ, wọn yóo foríbalẹ̀ fún ọ, wọn yóo sì mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ. Ìsìn ní Ọ̀run. Lẹ́yìn èyí mo tún rí ìran mìíran. Mo rí ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run. Mo wá gbọ́ ohùn kan bíi ti àkọ́kọ́.Tí ó dàbí ìgbà tí kàkàkí bá ń dún, tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní, “Gòkè wá níhìn-ín. N óo fi àwọn ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí hàn ọ́.” àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà á dojúbolẹ̀ níwájú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wọn a júbà ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae, wọn a fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n a máa wí pé, “Oluwa Ọlọrun wa, ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ògo, ati ọlá ati agbára.Nítorí ìwọ ni ó dá ohun gbogbo,ati pé nípa ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà,nípa rẹ ni a sì ṣe dá wọn.” Lẹsẹkẹsẹ ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo bá rí ìtẹ́ kan ní ọ̀run. Ẹnìkan jókòó lórí rẹ̀. Ojú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà dàbí òkúta iyebíye oríṣìí meji. Òṣùmàrè yí ìtẹ́ náà ká, ó ń tan ìmọ́lẹ̀ bí òkúta iyebíye. Àwọn ìtẹ́ mẹrinlelogun ni wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì jókòó lórí ìtẹ́ mẹrinlelogun náà. Wọ́n wọ aṣọ funfun, wọ́n dé adé wúrà. Mànàmáná ati ìró ààrá ń jáde láti ara ìtẹ́ tí ó wà láàrin. Ògùṣọ̀ meje tí iná wọn ń jó wà níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje. Iwájú ìtẹ́ náà dàbí òkun dígí, ó rí bíi yìnyín, ó mọ́ gaara. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan wà ní ààrin, wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Wọ́n ní ọpọlọpọ ojú níwájú ati lẹ́yìn. Ekinni dàbí kinniun, ekeji dàbí akọ mààlúù, ojú ẹkẹta jọ ti eniyan, ẹkẹrin sì dàbí idì tí ó ń fò. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà ní apá mẹfa. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ọpọlọpọ ojú. Wọn kì í sinmi tọ̀sán-tòru, wọ́n ń wí pé,“Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́!Oluwa Ọlọrun Olodumare.Ẹni tí ó ti wà, tí ó wà nisinsinyii,tí ó sì ń bọ̀ wá.” Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá fi ògo, ọlá ati ìyìn fún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae, Ìwé Kíká ati Ọ̀dọ́ Aguntan. Lẹ́yìn náà, mo rí ìwé kan ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́: wọ́n kọ nǹkan sí i ninu ati lóde, wọ́n sì fi èdìdì meje dì í. O ti sọ wọ́n di ìjọba ti alufaa láti máa sin Ọlọrun wa.Wọn yóo máa jọba ní ayé.” Bí mo tí ń wò, mo gbọ́ ohùn ọpọlọpọ àwọn angẹli tí wọ́n yí ìtẹ́ náà ká ati àwọn ẹ̀dá alààyè ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Àwọn angẹli náà pọ̀ pupọ: ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun àìmọye. Wọ́n ń kígbe pé,“Ọ̀dọ́ Aguntan tí a ti pa ni ó tọ́ síláti gba agbára, ọrọ̀, ọgbọ́n, ipá, ọlá, ògo ati ìyìn.” Mo bá tún gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tí ó wà lọ́run ati ní orílẹ̀ ayé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀, ati lórí òkun, ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu òkun, ń wí pé,“Ìyìn, ọlá, ògo, ati agbára ni ti ẹnití ó jókòó lórí ìtẹ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan lae ati laelae.” Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dáhùn pé, “Amin!” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun. Mo sì rí angẹli alágbára kan tí ń ké pẹlu ohùn rara pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, ati láti tú èdìdì rẹ̀?” Kò sí ẹnikẹ́ni ní ọ̀run, tabi lórí ilẹ̀ tabi nísàlẹ̀ ilẹ̀ tí ó lè ṣí ìwé náà tabi tí ó lè wò ó. Mo sunkún lọpọlọpọ nítorí kò sí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ láti ṣí ìwé náà ati láti wò ó. Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí wá sọ fún mi pé, “Má sunkún mọ́! Wò ó! Kinniun ẹ̀yà Juda, ọmọ Dafidi, ti borí. Ó le ṣí ìwé náà ó sì le tú èdìdì meje tí a fi dì í.” Mo bá rí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó dúró láàrin ìtẹ́ náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà yí i ká. Ọ̀dọ́ Aguntan náà dàbí ẹni pé wọ́n ti pa á. Ìwo meje ni ó ní ati ojú meje. Àwọn ojú meje yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje tí Ọlọrun rán sí gbogbo orílẹ̀ ayé. Ọ̀dọ́ Aguntan náà bá wá, ó sì gba ìwé náà ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́. Nígbà tí ó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn mẹrinlelogun náà dojúbolẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan yìí. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú hapu kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́, ati àwo wúrà kéékèèké, tí ó kún fún turari. Turari yìí ni adura àwọn eniyan Ọlọrun, àwọn onigbagbọ. Wọ́n wá ń kọ orin titun kan, pé,“Ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ìwé náà,ati láti tú èdìdì ara rẹ̀.Nítorí wọ́n pa ọ́,o sì ti fi ẹ̀jẹ̀ rẹ bá Ọlọrun ṣe ìràpadà eniyan,láti inú gbogbo ẹ̀yà,ati gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Ọ̀dọ́ Aguntan Tú Èdìdì Mẹfa. Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà nígbà tí ó ń tú ọ̀kan ninu àwọn èdìdì meje náà. Mo gbọ́ tí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin wí pẹlu ohùn tí ó dàbí ààrá, pé, “Wá!” Àwọn náà kígbe pé, “Oluwa mímọ́ ati olóòótọ́, nígbà wo ni ìwọ yóo ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí ìwọ yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára wọn?” A wá fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ funfun. A sọ fún wọn pé kí wọ́n sinmi díẹ̀ sí i títí iye àwọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ́ wọn ati àwọn arakunrin wọn yóo fi pé, àwọn tí wọn yóo pa láìpẹ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pa àwọn ti iṣaaju. Mo rí i nígbà tí ó tú èdìdì kẹfa pé ilẹ̀ mì tìtì. Oòrùn ṣókùnkùn, ó dàbí aṣọ dúdú. Òṣùpá wá dàbí ẹ̀jẹ̀. Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run já bọ́ sílẹ̀, bí ìgbà tí èso ọ̀pọ̀tọ́ bá já bọ́ lára igi rẹ̀ nígbà tí afẹ́fẹ́ líle bá fẹ́ lù ú. Ojú ọ̀run fẹ́ lọ bí ìgbà tí eniyan bá ká ẹní. Gbogbo òkè ati erékùṣù ni wọ́n kúrò ní ipò wọn. Àwọn ọba ayé, àwọn ọlọ́lá, àwọn ọ̀gágun, àwọn olówó, àwọn alágbára, ati gbogbo eniyan: ẹrú ati òmìnira, gbogbo wọn lọ sápamọ́ sinu ihò òkúta ati abẹ́ àpáta lára àwọn òkè. Wọ́n ń sọ fún àwọn òkè ati àpáta pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ pa wá mọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ati ibinu Ọ̀dọ́ Aguntan. Nítorí ọjọ́ ńlá ibinu wọn dé; kò sì sí ẹni tí ó lè dúró.” Mo bá rí ẹṣin funfun kan. Ẹni tí ó gùn ún mú ọrun ati ọfà lọ́wọ́. A fún un ní adé kan, ó bá jáde lọ bí aṣẹ́gun, ó ń ṣẹgun bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó tú èdìdì keji, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè keji ní, “Wá!” Ni ẹṣin mìíràn bá yọ jáde, òun pupa. A fi agbára fún ẹni tí ó gùn ún láti mú alaafia kúrò ní ayé, kí àwọn eniyan máa pa ara wọn. A wá fún un ní idà kan tí ó tóbi. Nígbà tí ó tú èdìdì kẹta, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹta ní, “Wá!” Mo rí ẹṣin dúdú kan. Ẹni tí ó gùn ún mú ìwọ̀n kan lọ́wọ́. Mo wá gbọ́ nǹkankan tí ó dàbí ohùn láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà, ó ní, “Páànù ọkà bàbà kan fún owó fadaka kan. Páànù ọkà baali mẹta fún owó fadaka kan. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan igi olifi ati ọtí waini.” Nígbà tí ó tú èdìdì kẹrin, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹrin ní, “Wá!” Mo wá rí ẹṣin kan tí àwọ̀ rẹ̀ rí bíi ti ewéko tútù. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Ikú. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ipò-òkú. A fún wọn ní àṣẹ láti fi idà ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn ati ẹranko burúkú pa idamẹrin ayé. Nígbà tí ó tú èdìdì karun-un, ní abẹ́ pẹpẹ ìrúbọ, mo rí ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́. Ọ̀kẹ́ Meje Ó Lé Ẹgbaaji (144,000) Eniyan Israẹli. Lẹ́yìn èyí, mo rí àwọn angẹli mẹrin tí wọ́n dúró ní igun mẹrẹẹrin ayé, tí wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹrẹẹrin ayé mú kí afẹ́fẹ́ má baà fẹ́ lórí ilẹ̀ ayé ati lórí òkun ati lára gbogbo igi. Wọ́n wá ń kígbe pé, “Ti Ọlọrun wa tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ati ti Ọ̀dọ́ Aguntan ni ìgbàlà.” Gbogbo àwọn angẹli tí ó dúró yí ìtẹ́ náà ká, ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n júbà Ọlọrun. Wọ́n ń wí pé, “Amin! Ìyìn, ògo, ọgbọ́n, ọpẹ́, ọlá, agbára ati ipá ni fún Ọlọrun wa lae ati laelae. Amin!” Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí bi mí pé, “Ta ni àwọn wọnyi tí a wọ̀ ní aṣọ funfun? Níbo ni wọ́n sì ti wá?” Mo bá dá a lóhùn pé, “Alàgbà, ìwọ ni ó mọ̀ wọ́n.” Ó wá sọ fún mi pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ti kọjá ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan. Nítorí èyí ni wọ́n ṣe wà níwájú ìtẹ́ Ọlọrun, tí wọn ń júbà tọ̀sán-tòru ninu Tẹmpili rẹ̀. Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà yóo máa bá wọn gbé. Ebi kò ní pa wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kò ní gbẹ wọ́n mọ́. Oòrùn kò ní pa wọ́n mọ́, ooru kankan kò sì ní mú wọn mọ́. Nítorí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó wà láàrin ìtẹ́ náà ni yóo máa ṣe olùtọ́jú wọn, yóo máa dà wọ́n lọ síbi ìsun omi ìyè.Ọlọrun yóo wá nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.” Mo bá tún rí angẹli mìíràn tí ó gòkè wá láti ìhà ìlà oòrùn, tí ó mú èdìdì Ọlọrun alààyè lọ́wọ́. Ó kígbe lóhùn rara sí àwọn angẹli mẹrẹẹrin tí a fún ní agbára láti ṣe ayé ní jamba. Ó ní, “Ẹ má ì tíì ṣe ilẹ̀ ayé ati òkun ati àwọn igi ní jamba títí tí a óo fi fi èdìdì sí àwọn iranṣẹ Ọlọrun wa níwájú.” Mo gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sí níwájú, wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ meje eniyan ó lé ẹgbaaji (144,000) láti inú gbogbo ẹ̀yà ọmọ Israẹli: Láti inú ẹ̀yà Juda ẹgbaafa (12,000) ni a fi èdìdì sí níwájú, láti inú ẹ̀yà Reubẹni, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Gadi, ẹgbaafa (12,000); láti inú ẹ̀yà Aṣeri, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Nafutali, ẹgbaafa (12,000) láti inú ẹ̀yà Manase, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Simeoni, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Lefi, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Isakari, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Sebuluni ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Josẹfu, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ẹgbaafa (12,000). Lẹ́yìn náà, mo rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ẹnikẹ́ni kò lè kà láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà, ati oríṣìíríṣìí èdè, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan. Wọ́n wọ aṣọ funfun. Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ lọ́wọ́. Ọ̀dọ́ Aguntan Tú Èdìdì Keje. Nígbà tí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tú èdìdì keje, gbogbo ohun tí ó wà ní ọ̀run parọ́rọ́ fún bí ìdajì wakati kan. Angẹli kẹta fun kàkàkí rẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá kan bá já bọ́ láti ọ̀run. Ó bẹ̀rẹ̀ sí jóná bí ògùṣọ̀. Ó bá já sinu ìdámẹ́ta àwọn odò ati ìsun omi. Orúkọ ìràwọ̀ náà ni “Igi-kíkorò.” Ó mú kí ìdámẹ́ta omi korò, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó sì kú nítorí oró tí ó wà ninu omi. Angẹli kẹrin fun kàkàkí rẹ̀, ìdámẹ́ta oòrùn kò bá lè ràn mọ́; ati ìdámẹ́ta òṣùpá, ati ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀. Ìdámẹ́ta wọn ṣókùnkùn, kò bá sí ìmọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta ọ̀sán ati ìdámẹ́ta òru. Mo tún rí ìran yìí. Mo gbọ́ tí idì kan tí ń fò ní agbede meji ọ̀run ń kígbe pé, “Ó ṣe! Ó ṣe! Ó ṣe fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé orí ilẹ̀ ayé nígbà tí kàkàkí tí àwọn angẹli mẹta yòókù fẹ́ fun bá dún!” Mo bá rí àwọn angẹli meje tí wọn máa ń dúró níwájú Ọlọrun, a fún wọn ní kàkàkí meje. Angẹli mìíràn tún dé, ó dúró lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ. Ó mú àwo turari tí wọ́n fi wúrà ṣe lọ́wọ́. A fún un ní turari pupọ kí ó fi rúbọ pẹlu adura gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun lórí pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú ìtẹ́ náà. Èéfín turari ati adura àwọn eniyan Ọlọrun gòkè lọ siwaju Ọlọrun láti ọwọ́ angẹli náà. Angẹli náà bá mú àwo turari yìí, ó bu iná láti orí pẹpẹ ìrúbọ kún inú rẹ̀, ó bá jù ú sí orí ilẹ̀ ayé. Ààrá bá bẹ̀rẹ̀ sí sán, mànàmáná ń kọ, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì. Àwọn angẹli meje tí wọ́n mú kàkàkí meje lọ́wọ́ bá múra láti fun kàkàkí wọn. Ekinni fun kàkàkí rẹ̀. Ni yìnyín ati iná pẹlu ẹ̀jẹ̀ bá tú dà sórí ilẹ̀ ayé. Ìdámẹ́ta ayé bá jóná, ati ìdámẹ́ta àwọn igi ati gbogbo koríko tútù. Angẹli keji fun kàkàkí rẹ̀. Ni a bá ju nǹkankan tí ó dàbí òkè gíga tí ó ń jóná sinu òkun. Ó bá sọ ìdámẹ́ta òkun di ẹ̀jẹ̀. Ìdámẹ́ta gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà ninu òkun ni wọ́n kú. Ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ ojú òkun ni wọ́n sì fọ́ túútúú. Angẹli karun-un wá fun kàkàkí rẹ̀, mo bá rí ìràwọ̀ kan tí ó ti ojú ọ̀run já bọ́ sí orí ilẹ̀ ayé. A fún ìràwọ̀ yìí ní kọ́kọ́rọ́ kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀. Wọ́n ní ìrù bíi ti àkeekèé tí wọ́n fi lè ta eniyan. A fún wọn ní agbára ninu ìrù wọn láti ṣe eniyan léṣe fún oṣù marun-un. Ọba wọn ni angẹli kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ní èdè Heberu ni Abadoni; ní èdè Giriki orúkọ rẹ̀ ni Apolioni. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni apanirun. Ìṣòro kinni kọjá; ṣugbọn ó tún ku meji lẹ́yìn èyí. Angẹli kẹfa fun kàkàkí rẹ̀. Mo bá gbọ́ ohùn kan láti ara àwọn ìwo tí ó wà lára pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú Ọlọrun. Ó sọ fún angẹli kẹfa tí ó mú kàkàkí lọ́wọ́ pé, “Dá àwọn angẹli mẹrin tí a ti dè ní odò ńlá Yufurate sílẹ̀.” Ni wọ́n bá dá àwọn angẹli mẹrin náà sílẹ̀. A ti pèsè wọn sílẹ̀ fún wakati yìí, ní ọjọ́ yìí, ninu oṣù yìí, ní ọdún yìí pé kí wọ́n pa ìdámẹ́ta gbogbo eniyan. Iye àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣin jẹ́ ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000,000). Mo gbọ́ iye wọn. Bí àwọn ẹṣin ọ̀hún ati àwọn tí ó gùn wọ́n ti rí lójú mi, lójú ìran nìyí: wọ́n gba ọ̀já ìgbàyà tí ó pọ́n bí iná, ó dàbí àyìnrín, ó tún rí bí imí-ọjọ́. Orí àwọn ẹṣin náà dàbí orí kinniun. Wọ́n ń yọ iná, ati èéfín ati imí-ọjọ́ lẹ́nu. Ohun ijamba mẹta yìí tí ó ń yọ jáde lẹ́nu wọn pa ìdá mẹta àwọn eniyan. Agbára àwọn ẹṣin wọnyi wà ní ẹnu wọn ati ní ìrù wọn. Nítorí ìrù wọn dàbí ejò, wọ́n ní orí. Òun sì ni wọ́n fi ń ṣe àwọn eniyan léṣe. Ó ṣí kànga náà, èéfín bá yọ láti inú kànga yìí, ó dàbí èéfín iná ìléru ńlá. Oòrùn ati ojú ọ̀run bá ṣókùnkùn nítorí èéfín tí ó jáde láti inú kànga náà. Àwọn eniyan tí ó kù, tí wọn kò kú ninu àjàkálẹ̀ àrùn yìí kò ronupiwada. Wọn kò kọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn tí wọn ń bọ sílẹ̀. Ṣugbọn wọ́n tún ń sin àwọn ẹ̀mí burúkú, ati oriṣa wúrà, ti fadaka, ti idẹ, ti òkúta, ati ti igi. Àwọn oriṣa tí kò lè ríran, wọn kò lè gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè rìn. Àwọn eniyan náà kò ronupiwada kúrò ninu ìwà ìpànìyàn, ìwà oṣó, ìwà àgbèrè ati ìwà olè wọn. Àwọn eṣú ti tú jáde láti inú èéfín náà, wọ́n lọ sí orí ilẹ̀ ayé. A fún wọn ní agbára bíi ti àkeekèé ayé. A sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe ohunkohun sí koríko orí ilẹ̀ tabi sí ewébẹ̀ tabi sí igi kan. Gbogbo àwọn eniyan tí kò bá ní èdìdì Ọlọrun ní iwájú wọn nìkan ni kí wọ́n ṣe léṣe. A kò gbà pé kí wọ́n pa wọ́n, oró ni kí wọ́n dá wọn fún oṣù marun-un, kí wọ́n dá wọn lóró bí ìgbà tí àkeekèé bá ta eniyan. Ní ọjọ́ náà àwọn eniyan yóo máa wá ikú ṣugbọn wọn kò ní kú; wọn yóo tọrọ ikú, ṣugbọn kò ní súnmọ́ wọn. Àwọn eṣú wọnyi dàbí àwọn ẹṣin tí a dì ní gàárì láti lọ sójú ogun. Adé wà ní orí wọn tí ó dàbí adé wúrà. Ojú wọn dàbí ojú eniyan. Irun wọn dàbí irun obinrin. Eyín wọn dàbí ti kinniun. Wọ́n ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin. Ìró ìyẹ́ wọn dàbí ìró ọpọlọpọ ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin tí wọn ń sáré lọ sójú ogun. Ìkíni. Èmi Paulu, iranṣẹ Kristi Jesu, ni mò ń kọ ìwé yìí. Ọlọrun pè mí, ó fi mí ṣe òjíṣẹ́, ó sì yà mí sọ́tọ̀ láti máa waasu ìyìn rere rẹ̀. Mo sì ń bẹ̀bẹ̀ nígbà gbogbo ninu adura mi pé, ó pẹ́ ni, ó yá ni, kí n rí ààyè láti wá sọ́dọ̀ yín, bí Ọlọrun bá fẹ́. Mò ń dàníyàn láti ri yín, kí n lè fun yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí tí yóo túbọ̀ fun yín lágbára. Ohun tí mò ń sọ ni pé mo fẹ́ wà láàrin yín kí n baà lè ní ìwúrí nípa igbagbọ yín, kí ẹ̀yin náà ní ìwúrí nípa igbagbọ mi. Kò yẹ kí ẹ má mọ̀, ará, pé ní ìgbà pupọ ni mo ti fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín, kí n lè ní èso láàrin yín bí mo ti ní láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, ṣugbọn nǹkankan ti ń dí mi lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ títí di àkókò yìí. Nítorí pé ati àwọn Giriki tí wọ́n jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n, ati àwọn kògbédè tí kò mọ nǹkan, gbogbo wọn ni mo jẹ ní gbèsè. Ìdí rẹ̀ nìyí tí mo ṣe ń dàníyàn láti waasu ìyìn rere fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Romu náà. Ojú kò tì mí láti waasu ìyìn rere Jesu, nítorí ìyìn rere yìí ni agbára Ọlọrun, tí a fi ń gba gbogbo àwọn tí ó bá gbà á gbọ́ là. Ó kọ́kọ́ lo agbára yìí láàrin àwọn Juu, lẹ́yìn náà ó lò ó láàrin àwọn Giriki. Ninu ìyìn rere yìí ni a ti ń fi ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre hàn wá: nípa igbagbọ ni, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí igbagbọ ni ẹni tí a bá dá láre yóo fi yè.” Ojú ọ̀run ti ṣí sílẹ̀, Ọlọrun sì ń tú ibinu rẹ̀ sórí gbogbo eniyan nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú tí wọn ń hù, tí wọ́n fi ń ṣe ìdènà fún òtítọ́. Nítorí ohun tí eniyan lè mọ̀ nípa Ọlọrun ti hàn sí wọn, Ọlọrun ni ó ti fihàn wọ́n. Bí a bá wo inú Ìwé Mímọ́, a óo rí i pé àwọn wolii ti kéde ìyìn rere náà tẹ́lẹ̀ rí. Láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ayé ni ìwà ati ìṣe Ọlọrun, tí a kò lè fi ojú rí ati agbára ayérayé rẹ̀, ti hàn gedegbe ninu àwọn ohun tí ó dá. Nítorí èyí, irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kò ní àwáwí. Wọ́n mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò júbà rẹ̀ bí Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, gbogbo èrò wọn di asán, òye ọkàn wọn sì ṣókùnkùn. Wọ́n ń ṣe bí ẹni pé wọ́n gbọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ya òmùgọ̀. Wọ́n yí ògo Ọlọrun tí kò lè bàjẹ́ pada sí àwòrán ẹ̀dá tí yóo bàjẹ́; bíi àwòrán eniyan, ẹyẹ, ẹranko ati ejò. Nítorí náà Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ láti máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn. Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọrun pada sí irọ́. Wọ́n ń bọ nǹkan tí Ọlọrun dá, wọ́n ń tẹríba fún wọn, dípò èyí tí wọn ìbá fi máa sin ẹni tí ó dá wọn, ẹni tí ìyìn yẹ fún títí lae. Amin. Nítorí náà, Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí ó ti eniyan lójú. Àwọn obinrin wọn ń bá ara wọn ṣe ohun tí kò bójú mu. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọkunrin wọn. Dípò tí ọkunrin ìbá máa fi bá obinrin lòpọ̀, ọkunrin ati ọkunrin ni wọ́n ń dìde sí ara wọn ninu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn. Ọkunrin ń bá ọkunrin ṣe ohun ìtìjú, wọ́n wá ń jèrè ìṣekúṣe wọn. Nígbà tí wọn kò ka ìmọ̀ Ọlọrun sí, Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ pẹlu ọkàn wọn tí kò tọ́, kí wọn máa ṣe àwọn ohun tí kò yẹ. Wọ́n wá kún fún oríṣìíríṣìí ìwà burúkú: ojúkòkòrò, ìkà, owú jíjẹ, ìpànìyàn, ìrúkèrúdò, ẹ̀tàn, inú burúkú. Olófòófó ni wọ́n, Ìyìn rere Ọmọ Ọlọrun tí a bí ninu ìdílé Dafidi nípa ti ara. ati abanijẹ́; wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun. Wọ́n jẹ́ aláfojúdi, onigbeeraga, afọ́nnu, ati elérò burúkú; wọn kì í gbọ́ràn sí òbí lẹ́nu; wọn kò sì ní ẹ̀rí ọkàn. Aláìṣeégbẹ́kẹ̀lé ni wọ́n, aláìnífẹ̀ẹ́, ati aláìláàánú. Wọ́n mọ ìlànà ti Ọlọrun; wọ́n mọ̀ pé ikú ni ó tọ́ sí àwọn tí wọn bá ń hu irú ìwà wọnyi; sibẹ kì í ṣe pé wọ́n ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ nìkan, wọ́n tún ń kan sáárá sí àwọn tí ń hùwà bẹ́ẹ̀. Ọmọ rẹ̀ yìí ni Ọlọrun fi agbára Ẹ̀mí Mímọ́ yàn nígbà tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú. Òun náà ni Jesu Kristi Oluwa wa, nípa ẹni tí a ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà, tí a sì gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní orúkọ rẹ̀, pé kí gbogbo eniyan lè gba Jesu gbọ́, kí wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Ẹ̀yin tí mò ń kọ ìwé yìí sí náà wà lára àwọn tí Jesu Kristi pè. Gbogbo ẹ̀yin àyànfẹ́ Ọlọrun tí ẹ wà ní Romu, ẹ̀yin tí a pè láti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀.Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi, kí ó wà pẹlu yín. Kí á tó máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi nípasẹ̀ Jesu Kristi nítorí gbogbo yín; nítorí àwọn eniyan ń ròyìn igbagbọ yín ní gbogbo ayé. Ọlọrun, tí mò ń fọkàn sìn bí mo ti ń waasu ìyìn rere Ọmọ rẹ̀, ni ẹlẹ́rìí mi pé mò ń ranti yín láì sinmi. Ìgbàlà fún Gbogbo Eniyan. Ẹ̀yin ará mi, ìfẹ́ ọkàn mi, ati ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọrun fún àwọn Juu, àwọn eniyan mi ni pé kí á gbà wọ́n là. Nítorí pẹlu ọkàn ni a fi ń gbàgbọ́ láti rí ìdáláre gbà. Ṣugbọn ẹnu ni a fi ń jẹ́wọ́ láti rí ìgbàlà. Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ tí ojú yóo tì.” Nítorí kò sí ìyàtọ̀ kan láàrin Juu ati Giriki. Nítorí Ọlọrun kan náà ni Oluwa gbogbo wọn, ọlá rẹ̀ sì pọ̀ tó fún gbogbo àwọn tí ó bá ń ké pè é. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” Ṣugbọn báwo ni wọn yóo ṣe ké pe ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Báwo ni wọn yóo ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúròó rẹ̀ gbọ́? Báwo ni wọn yóo ṣe gbúròó rẹ̀ láìsí àwọn tí ó ń kéde rẹ̀? Báwo ni àwọn kan yóo ṣe lọ kéde rẹ̀ láìjẹ́ pé a bá rán wọn lọ? Ó wà ninu Ìwé Mímọ́ pé, “Àwọn tí ó mú ìyìn rere wá mà mọ̀ ọ́n rìn o!” Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gba ìyìn rere yìí gbọ́. Aisaya ṣá sọ ọ́ pé, “Oluwa, ta ni ó gba ohun tí a sọ gbọ́?” Ṣebí ohun tí a bá gbọ́ ni à ń gbàgbọ́, ohun tí a sì gbọ́ yìí ni ọ̀rọ̀ Kristi? Mo wá ń bèèrè, “Ṣé wọn kò ì tíì gbọ́ ni?” Wọ́n kúkú ti gbọ́, nítorí a rí i kà ninu Ìwé Mímọ́ pé,“Ìró wọn ti dé gbogbo orílẹ̀-èdè,àní, ọ̀rọ̀ wọn ti dé òpin ayé.” Mo tún bèèrè: Àbí Israẹli kò mọ̀ ni? Ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ohun tí Mose kọ́kọ́ sọ; ó ní,“N óo jẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe orílẹ̀-èdè mu yín jowú,N óo sì jẹ́ kí orílẹ̀-èdè tí kò lóye mú kí ara ta yín.” Nítorí mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara láti sin Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò ní òye bí ó ti yẹ kí wọ́n sìn ín. Aisaya pàápàá kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ kọ́ òun lẹ́nu, ó ní,“Àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi,àwọn tí kò bèèrè mi ni mo fi ara hàn fún.” Ṣugbọn ohun tí ó ní Ọlọrun wí fún Israẹli ni pé, “Láti òwúrọ̀ títí di alẹ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọn aláìgbọràn ati alágídí eniyan.” Wọn kò tíì ní òye ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dáni láre, nítorí náà wọ́n wá ọ̀nà ti ara wọn, wọn kò sì fi ara wọn sábẹ́ ètò tí Ọlọrun ṣe fún ìdániláre. Nítorí Kristi ti fi òpin sí Òfin láti mú gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ rí ìdáláre níwájú Ọlọrun. Mose kọ sílẹ̀ báyìí nípa ìdáláre tí Òfin lè fúnni pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa wọ́n mọ́, yóo ti ipa wọn rí ìyè.” Ṣugbọn báyìí ni Ìwé Mímọ́ wí nípa ìdáláre tí à ń gbà nípa igbagbọ, pé, “Má ṣe wí ní ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóo gòkè lọ sọ́run?’ ” (Èyí ni láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀.) “Tabi, ‘Ta ni yóo wọ inú ọ̀gbun ilẹ̀ lọ?’ ” (Èyí ni, láti mú Kristi jáde kúrò láàrin àwọn òkú.) Ṣugbọn ohun tí ó sọ ni pé, “Ọ̀rọ̀ náà wà nítòsí rẹ, àní, ó wà lẹ́nu rẹ ati lọ́kàn rẹ.” Èyí ni ọ̀rọ̀ igbagbọ tí à ń waasu, pé: bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ jẹ́wọ́ pé, “Jesu ni Oluwa,” tí o sì gbàgbọ́ lọ́kàn rẹ pé Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú, a óo gbà ọ́ là. Àánú Ọlọrun fún Israẹli. Ǹjẹ́, mo bèèrè: ṣé Ọlọrun ti wá kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀ ni? Rárá o! Ọmọ Israẹli ni èmi fúnra mi. Ìran Abrahamu ni mí, láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Bẹnjamini. Jẹ́ kí ojú wọn ṣókùnkùn,kí wọn má lè ríran.Jẹ́ kí ẹ̀yìn wọn tẹ̀,kí wọn má lè nàró mọ́.” Mo tún bèèrè: ǹjẹ́ nígbà tí àwọn Juu kọsẹ̀, ṣé wọ́n ṣubú gbé ni? Rárá o! Ṣugbọn nítorí ìṣìnà wọn ni ìgbàlà fi dé ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí àwọn Juu baà lè máa jowú. Ǹjẹ́ bí ìṣìnà wọn bá ṣe ayé ní anfaani, bí ìkùnà wọn bá ṣe orílẹ̀-èdè yòókù ní anfaani, báwo ni anfaani náà yóo ti pọ̀ tó nígbà tí gbogbo wọn bá ṣe ojúṣe wọn? Ẹ̀yin ará, tí ẹ kì í ṣe Juu ni mò ń bá sọ̀rọ̀ nisinsinyii. Níwọ̀n ìgbà tí mo jẹ́ Aposteli láàrin yín, mò ń ṣe àpọ́nlé iṣẹ́ mi, pé bóyá mo lè ti ipa bẹ́ẹ̀ mú àwọn eniyan mi jowú yín, kí n lè gba díẹ̀ ninu wọn là. Nítorí bí kíkọ̀ tí Ọlọrun kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bá mú kí aráyé bá Ọlọrun rẹ́, kí ni yóo ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbà wọ́n mọ́ra? Ǹjẹ́ òkú pàápàá kò ní jí dìde? Bí a bá ya ìyẹ̀fun tí a kọ́kọ́ rí ninu ìkórè sí mímọ́, a ti ya burẹdi tí a fi ṣe sí mímọ́. Bí a bá ya gbòǹgbò igi sí mímọ́, a ti ya àwọn ẹ̀ka igi náà sí mímọ́. A gé díẹ̀ ninu àwọn ẹ̀ka igi olifi inú oko kúrò, a wá lọ́ ẹ̀ka igi olifi inú tí ó lalẹ̀ hù ninu ìgbẹ́ dípò rẹ̀. Ẹ̀yin, tí ẹ kì í ṣe Juu, wá dàbí ẹ̀ka igi olifi tí ó lalẹ̀ hù ninu ìgbẹ́. Ẹ wá jọ ń rí oúnjẹ ati agbára láti ibìkan náà pẹlu àwọn Juu, tí ó jẹ́ igi olifi inú oko. Nítorí náà, má ṣe fọ́nnu bí ẹni pé o sàn ju àwọn ẹ̀ka ti àkọ́kọ́ lọ. Tí o bá ń fọ́nnu, ranti pé kì í ṣe ìwọ ni ò ń gbé gbòǹgbò ró. Ìwọ yóo wá wí pé, “Gígé ni a gé àwọn ẹ̀ka kúrò kí á lè fi mí rọ́pò wọn.” Ọlọrun kò kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀, àwọn tí ó ti yàn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Tabi ẹ kò mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ninu ìtàn Elija? Ó ní, Lóòótọ́ ni. A gé wọn kúrò nítorí wọn kò gbàgbọ́, nípa igbagbọ ni ìwọ náà fi wà ní ipò rẹ. Mú èrò ìgbéraga kúrò lọ́kàn rẹ, kí o sì ní ọkàn ìbẹ̀rù. Nítorí bí Ọlọrun kò bá dá àwọn tí ó jẹ́ bí ẹ̀ka igi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ sí, kò ní dá ìwọ náà sí. Nítorí náà ṣe akiyesi ìyọ́nú Ọlọrun ati ìrorò rẹ̀. Ó rorò sí àwọn tí ó kùnà. Yóo yọ́nú sí ọ, tí o bá farabalẹ̀ gba ìyọ́nú rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo gé ìwọ náà kúrò pẹlu. Àwọn Juu tí a gé kúrò yóo tún bọ́ sí ipò wọn pada, bí wọn bá kọ ọ̀nà aigbagbọ sílẹ̀. Ọlọrun lágbára láti tún lọ́ wọn pada sí ibi tí ó ti gé wọn. Ìwọ tí ó jẹ́ bí ẹ̀ka igi olifi tí ó la ilẹ̀ hù ninu ìgbẹ́, tí a lọ́ mọ́ ara igi olifi inú oko, tí ẹ̀dá wọn yàtọ̀ sí ara wọn, báwo ni yóo ti rọrùn tó láti tún lọ́ àwọn tí ó jẹ́ ara igi olifi inú oko tẹ́lẹ̀ mọ́ ara igi tí a ti gé wọn kúrò! Ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ ohun àṣírí yìí, kí ẹ má baà ro ara yín jù bí ó ti yẹ lọ. Òun ni pé, apá kan ninu àwọn ọmọ Israẹli yóo jẹ́ alágídí ọkàn títí di ìgbà tí iye àwọn tí a yàn láti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo fi dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Lẹ́yìn náà, a óo wá gba gbogbo Israẹli là. A ti kọ ọ́ sílẹ̀ pé, “Olùdáǹdè yóo wá láti Sioni,yóo mú gbogbo ìwàkiwà kúrò ní ilé Jakọbu. Èyí ni majẹmu tí n óo bá wọn dá, lẹ́yìn tí mo bá mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.” Nítorí pé àwọn Juu kọ ìyìn rere, wọ́n sọ ara wọn di ọ̀tá Ọlọrun, èyí sì ṣe yín láǹfààní. Ṣugbọn níwọ̀n ìgbà tí Ọlọrun ti yàn wọ́n nítorí àwọn baba-ńlá orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ sibẹ. Nítorí Ọlọrun kò jẹ́ kábàámọ̀ pé òun fún ẹnìkan ní ẹ̀bùn kí ó wá gbà á pada. “Oluwa, wọ́n ti pa àwọn wolii rẹ, wọ́n ti wó pẹpẹ ìrúbọ rẹ, èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá mi láti pa.” Bí ẹ̀yin fúnra yín ti jẹ́ aláìgbọràn sí Ọlọrun nígbà kan rí, ṣugbọn tí ó wá ṣàánú yín nígbà tí àwọn Juu ṣàìgbọràn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, nisinsinyii tí ẹ̀yin náà rí àánú gbà, wọ́n di aláìgbọràn, kí àwọn náà lè rí àánú Ọlọrun gbà. Nítorí Ọlọrun ti ka gbogbo eniyan sí ẹlẹ́bi nítorí àìgbọràn wọn, kí ó lè ṣàánú fún gbogbo wọn papọ̀. Ọlà ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ Ọlọrun mà kúkú jinlẹ̀ pupọ o! Àwámárìídìí ni ìdájọ́ rẹ̀. Iṣẹ́ rẹ̀ tayọ ohun tí ẹ̀dá lè tú wò. Ìwé Mímọ́ sọ báyìí pé: “Ta ni mọ inú Ọlọrun?Ta ni olùbádámọ̀ràn rẹ̀? Ta ni ó yá a ní ohunkohun rí tí ó níláti san án pada?” Nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ohun gbogbo wà, láti ọwọ́ rẹ̀ ni ohun gbogbo ti ń wá, nítorí tirẹ̀ sì ni ohun gbogbo ṣe wà. Tirẹ̀ ni ògo títí ayérayé. Amin. Ṣugbọn kí ni Ọlọrun wí fún un? Ó ní “Ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan ṣì kù fún mi tí wọn kò tíì wólẹ̀ bọ Baali rí.” Bẹ́ẹ̀ náà ló rí ní àkókò yìí, àwọn kan kù tí Ọlọrun yàn nítorí oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Tí ó bá wá jẹ́ pé nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni Ọlọrun fi yàn wọ́n, kò tún lè jẹ́ nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, oore-ọ̀fẹ́ kò ní jẹ́ oore-ọ̀fẹ́ mọ́. Kí wá ni? Ohun tí Israẹli ń wá kò tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ṣugbọn ó tẹ àwọn díẹ̀ tí a yàn ninu wọn lọ́wọ́. Etí àwọn yòókù di sí ìpè Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ọlọrun fún wọn ní iyè tí ó ra,ojú tí kò ríran,ati etí tí kò gbọ́ràn títí di òní olónìí.” Dafidi náà sọ pé, “Jẹ́ kí àsè wọn di tàkúté ati àwọ̀n,kí ó gbé wọn ṣubú,kí ó mú ẹ̀san bá wọn. Ayé Titun ninu Kristi. Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ̀yin ará, mo fỌlọrun aláàánú bẹ̀ yín pé kí ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ bí ẹbọ mímọ́ tí ó yẹ láti fi sin Ọlọrun. Èyí ni iṣẹ́ ìsìn tí ó yẹ yín. Ẹ ní ìfẹ́ láàrin ara yín bíi mọ̀lẹ́bí. Ní ti bíbu ọlá fún ara yín, ẹ máa fi ti ẹnìkejì yín ṣiwaju. Ẹ má jẹ́ kí ìtara yín rẹ̀yìn. Ẹ máa sin Oluwa tọkàntọkàn. Ẹ máa yọ̀ nítorí ìrètí tí ẹ ní. Ẹ máa fara da ìṣòro, kí ẹ sì tẹra mọ́ adura. Ẹ pín àwọn aláìní láàrin àwọn onigbagbọ ninu ohun ìní yín. Ẹ máa ṣaájò àwọn àlejò. Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń ṣe inúnibíni yín, kàkà kí ẹ ṣépè, ìre ni kí ẹ máa sú fún wọn. Àwọn tí ń yọ̀, ẹ bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sunkún, ẹ bá wọn sunkún. Ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ má ṣe gbèrò ohun gíga-gíga, ṣugbọn ẹ máa darapọ̀ mọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara yín. Ẹ má máa fi burúkú san burúkú. Ẹ jẹ́ kí èrò ọkàn yín sí gbogbo eniyan máa jẹ́ rere. Ẹ sa ipá yín, níwọ̀n bí ó bá ti ṣeéṣe, láti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu gbogbo eniyan. Ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ má máa gbẹ̀san, dípò bẹ́ẹ̀, ẹ máa fún Ọlọrun láàyè láti fi ibinu rẹ̀ hàn. Nítorí Ọlọrun sọ ninu àkọsílẹ̀ pé, “Tèmi ni ẹ̀san, Èmi yóo sì gbẹ̀san.” Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí ẹ para dà, kí ọkàn yín di titun, kí ẹ lè mòye ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó yẹ, tí ó sì pé. Ó wà ní àkọsílẹ̀ mìíràn pé, “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ, bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu. Nítorí nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóo wa ẹ̀yinná ìtìjú lé e lórí.” Má jẹ́ kí nǹkan burúkú borí rẹ, ṣugbọn fi ohun rere ṣẹgun nǹkan burúkú. Nítorí nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fún mi, mò ń sọ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan láàrin yín pé kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ jù bí ó ti yẹ lọ. Ṣugbọn kí olukuluku ronú níwọ̀n, kí ó máa ṣe jẹ́jẹ́, níwọ̀nba bí Ọlọrun ti pín ẹ̀bùn igbagbọ fún un. Nítorí bí a ti ní ẹ̀yà ara pupọ ninu ara kan, tí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara wọnyi kì í sìí ṣe iṣẹ́ kan náà, bẹ́ẹ̀ gan-an ni gbogbo wa, bí á tilẹ̀ pọ̀, ara kan ni wá ninu Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa sì jẹ́ ẹ̀yà ara ẹnìkejì rẹ̀. Bí a ti ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pín oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí á lò wọ́n. Bí ẹnìkan bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, kí ó lò ó gẹ́gẹ́ bí igbagbọ rẹ̀ ti mọ. Bí ó bá jẹ́ ẹ̀bùn láti darí ètò ni, kí á lò ó láti darí ètò. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn ìkọ́ni, kí ó lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Bí ó bá ní ẹ̀bùn láti fúnni ní ọ̀rọ̀ ìwúrí, kí ó lò ó láti lé ìrẹ̀wẹ̀sì jìnnà. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, kí ó ṣe é pẹlu ọkàn kan. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn láti ṣe aṣiwaju, kí ó ṣe é tọkàntọkàn. Ẹni tí ó bá ń ṣiṣẹ́ àánú, kí ó fọ̀yàyà ṣe é. Ìfẹ́ yín kò gbọdọ̀ ní ẹ̀tàn ninu. Ẹ kórìíra nǹkan burúkú. Ẹ fara mọ́ àwọn nǹkan rere. Ipò Àwọn Aláṣẹ Ìlú. Gbogbo eniyan níláti fi ara wọn sí abẹ́ àwọn aláṣẹ ìlú, nítorí kò sí àṣẹ kan àfi èyí tí Ọlọrun bá lọ́wọ́ sí. Àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, Ọlọrun ni ó yàn wọ́n. Ìfẹ́ kò jẹ́ ṣe nǹkan burúkú sí ẹnìkejì. Nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin. Ó yẹ kí ẹ mọ irú àkókò tí a wà yìí, kí ẹ tají lójú oorun. Nítorí àkókò ìgbàlà wa súnmọ́ tòsí ju ìgbà tí a kọ́kọ́ gbàgbọ́ lọ. Alẹ́ ti lẹ́ tipẹ́. Ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa iṣẹ́ òkùnkùn tì, kí á múra gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun ìmọ́lẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á máa rìn bí ó ti yẹ ní ọ̀sán, kí á má wà ninu àwùjọ aláriwo ati ọ̀mùtí, kí á má máa ṣe ìṣekúṣe, kí á má máa hu ìwà wọ̀bìà, kí á má máa ṣe aáwọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí á má máa jowú. Ṣugbọn ẹ gbé Oluwa Jesu Kristi wọ̀ bí ihamọra. Ẹ má jẹ́ kí á máa gbèrò láti ṣe àwọn ohun tí ara fẹ́. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fojú di aláṣẹ ń tàpá sí àṣẹ Ọlọrun. Àwọn tí ó bá sì ṣe àfojúdi yóo forí ara wọn gba ìdájọ́. Nítorí àwọn aláṣẹ kò wà láti máa dẹ́rù ba àwọn tí ó ń ṣe rere. Àwọn oníṣẹ́ ibi ni ó ń bẹ̀rù àwọn aláṣẹ. Ṣé o kò fẹ́ kí òfin máa já ọ láyà? Máa ṣe ohun rere, o óo sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣòfin. Nítorí iṣẹ́ Oluwa ni àwọn aṣòfin ń ṣe fún rere rẹ. Ṣugbọn bí o bá ń ṣe nǹkan burúkú, o jẹ́ bẹ̀rù! Nítorí kì í ṣe lásán ni idà tí ó wà lọ́wọ́ wọn. Ọlọrun ni ó gbà wọ́n sí iṣẹ́ láti fi ibinu gbẹ̀san lára àwọn tí ó bá ń ṣe nǹkan burúkú. Nítorí náà, eniyan níláti foríbalẹ̀, kì í ṣe nítorí ẹ̀rù ibinu Ọlọrun nìkan, ṣugbọn nítorí pé ẹ̀rí ọkàn wa pàápàá sọ fún wa pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Ìdí kan náà nìyí tí ẹ fi ń san owó-orí. Iṣẹ́ Ọlọrun ni àwọn aláṣẹ ń ṣe, nǹkankan náà tí wọ́n tẹra mọ́ nìyí. Nítorí náà, ẹ san ohun tí ẹ bá jẹ ẹnikẹ́ni pada fún un. Ẹ san owó-orí fún ẹni tí owó-orí tọ́ sí. Ẹ san owó-odè fún ẹni tí owó-odè yẹ. Ẹ bu ọlá fún ẹni tí ọlá bá yẹ. Ẹ má jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ohunkohun, àfi gbèsè ìfẹ́ tí ẹ jẹ ara yín. Nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹnìkejì ti pa gbogbo òfin mọ́. “Fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ” ni kókó òfin bíi, “Má ṣe àgbèrè, má jalè, má ṣe ojúkòkòrò,” ati èyíkéyìí tí ó kù ninu òfin. Má Ṣe Dá Ẹnìkejì Rẹ lẹ́jọ́. Ẹ fa àwọn tí igbagbọ wọn kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́ra, kì í ṣe láti máa bá wọn jiyàn lórí ohun tí kò tó iyàn. Kí ni ìdí tí o fi ń dá arakunrin rẹ lẹ́jọ́? Sọ ọ́ kí á gbọ́! Tabi kí ló dé tí ò ń fi ojú tẹmbẹlu arakunrin rẹ? Gbogbo wa mà ni a óo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun! Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Oluwa fi ara rẹ̀ búra, ó ní,‘Èmi ni gbogbo orúnkún yóo kúnlẹ̀ fún,Èmi ni gbogbo ẹnu yóo pè ní Ọlọrun.’ ” Nítorí náà, olukuluku wa ni yóo sọ ti ẹnu ara rẹ̀ níwájú Ọlọrun. Ẹ má ṣe jẹ́ kí á máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ìpinnu kan tí à bá ṣe ni pé, kí á má ṣe fi ohun ìkọsẹ̀ kan, tabi ohunkohun tí yóo ṣi arakunrin wa lọ́nà, sí ojú ọ̀nà rẹ̀. Mo mọ èyí, ó sì dá mi lójú nípa àṣẹ Oluwa Jesu pé kò sí ohunkohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ ní jíjẹ fún ara rẹ̀. Ṣugbọn tí ẹnìkan bá ka nǹkan sí èèwọ̀, èèwọ̀ ni fún irú ẹni bẹ́ẹ̀. Nítorí bí o bá mú ìdààmú bá arakunrin rẹ nípa ọ̀ràn oúnjẹ tí ò ń jẹ, a jẹ́ pé, kì í ṣe ìfẹ́ ni ń darí ìgbésí-ayé rẹ mọ́. Má jẹ́ kí oúnjẹ tí ò ń jẹ mú ìparun bá ẹni tí Jesu ti ìtorí rẹ̀ kú. Má ṣe fi ààyè sílẹ̀ fún ìsọkúsọ nípa àwọn ohun tí ẹ kà sí nǹkan rere. Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ọ̀ràn nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu, ọ̀ràn òdodo, alaafia ati ayọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni. Ẹni tí ó bá ń sin Kristi báyìí jẹ́ ẹni tí inú Ọlọrun dùn sí, tí àwọn eniyan sì gbà fún. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa lépa àwọn nǹkan tí ń mú alaafia wá, ati àwọn nǹkan tí yóo yọrí sí ìdàgbàsókè láàrin ara wa. Ẹnìkan ní igbagbọ pé kò sí ohun tí òun kò lè jẹ, ṣugbọn ẹni tí igbagbọ rẹ̀ kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ rọra ń jẹ ẹ̀fọ́ ní tirẹ̀. Ẹ má ṣe tìtorí oúnjẹ ba iṣẹ́ Ọlọrun jẹ́. A lé sọ pé kò sí oúnjẹ kan tí kò dára, ṣugbọn nǹkan burúkú ni fún ẹni tí ó bá ń jẹ oúnjẹ kan tí ó di nǹkan ìkọsẹ̀ fún ẹlòmíràn. Ó dára bí o kò bá jẹ ẹran, tabi kí o mu ọtí, tabi kí o ṣe ohunkohun tí yóo mú arakunrin rẹ kọsẹ̀. Bí ìwọ bá ní igbagbọ ní tìrẹ, jẹ́ kí igbagbọ tí o ní wà láàrin ìwọ ati Ọlọrun rẹ. Olóríire ni ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò bá dá lẹ́bi lórí nǹkan tí ó bá gbà láti ṣe. Ṣugbọn bí ẹni tí ó ń ṣiyèméjì bá jẹ kinní kan, ó jẹ̀bi, nítorí tí kò jẹ ẹ́ pẹlu igbagbọ. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ohunkohun tí eniyan kò bá ṣe pẹlu igbagbọ. Kí ẹni tí ń jẹran má fi ojú tẹmbẹlu ẹni tí kì í jẹ. Kí ẹni tí kì í jẹ má sì ṣe dá ẹni tí ó ń jẹ lẹ́bi, nítorí Ọlọrun ti gbà á. Ta ni ìwọ tí ò ń dá ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Kì báà dúró, kì báà sì ṣubú, ọ̀gá rẹ̀ nìkan ni ìdájọ́ tọ́ sí. Yóo tilẹ̀ dúró ni, nítorí Oluwa lè gbé e ró. Ẹnìkan ka ọjọ́ kan sí ọjọ́ pataki ju ọjọ́ mìíràn lọ, ẹlòmíràn ka gbogbo ọjọ́ sí bákan náà. Ẹ jẹ́ kí olukuluku pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ nípa irú ọ̀ràn báwọ̀nyí. Ẹni tí ó gbé ọjọ́ kan ga ju ọjọ́ mìíràn lọ, ti Oluwa ni ó ń rò. Ẹni tí ó ń jẹ oríṣìíríṣìí oúnjẹ, ó ń jẹ ẹ́ nítorí Oluwa. Ọpẹ́ ni ó ń fi fún Ọlọrun. Ẹni tí kò jẹ, kò jẹ ẹ́ nítorí Oluwa, ọpẹ́ ni òun náà ń fi fún Ọlọrun. Kò sí ẹni tí ó lè wà láàyè fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni, kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, òun nìkan ni ikú òun kàn. Bí a bá wà láàyè, Oluwa ni a wà láàyè fún. Bí a bá sì kú, Oluwa ni a kú fún. Nítorí náà, ààyè wa ni o, òkú wa ni o, ti Oluwa ni wá. Ìdí tí Kristi fi kú nìyí, tí ó sì tún jí, kí ó lè jẹ́ Oluwa àwọn òkú ati ti àwọn alààyè. Ẹ Máa Ṣe Ohun Tí Ó Tẹ́ Ẹlòmíràn lọ́rùn. Ó yẹ kí àwa tí a jẹ́ alágbára ninu igbagbọ máa fara da àwọn nǹkan tí àwọn tí igbagbọ wọn kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ bá ń ṣiyèméjì lé lórí. A kò gbọdọ̀ máa tẹ́ ara wa nìkan lọ́rùn. Ó tún sọ pé, “Ẹ bá àwọn eniyan rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè.” Ó tún sọ pé, “Ẹ yin Oluwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdèkí gbogbo eniyan yìn ín.” Aisaya tún sọ pé, “Gbòǹgbò kan yóo ti ìdílé Jese yọ,yóo yọ láti pàṣẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè,nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí àwọn orílẹ̀-èdè wà.” Kí Ọlọrun tí ó ń fúnni ní ìrètí fi ayọ̀ tí ò kún ati alaafia fun yín nípa igbagbọ yín, kí ẹ lè máa dàgbà ninu ìrètí tí ẹ ní ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀yin ará, ó dá mi lójú pé ẹ̀yin fúnra yín kún fún inú rere, ẹ ní ìmọ̀ ohun gbogbo, ẹ mọ irú ìmọ̀ràn tí ẹ lè máa gba ara yín. Sibẹ, mo ti fi ìgboyà tẹnumọ́ àwọn kókó ọ̀rọ̀ mélòó kan ninu ìwé yìí, láti ran yín létí nípa wọn. Mo ní ìgboyà láti sọ wọ́n fun yín nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fún mi láti jẹ́ iranṣẹ Kristi Jesu sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu. Mò ń ṣe iṣẹ́ alufaa láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi nípa wiwaasu ìyìn rere Ọlọrun, kí wọ́n lè jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọrun, ọrẹ tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti yà sí mímọ́. Nítorí náà, mo ní ohun tí mo lè fi ṣògo ninu Kristi Jesu, ninu iṣẹ́ tí mò ń ṣe fún Ọlọrun. N kò jẹ́ sọ nǹkankan àfi àwọn nǹkan tí Kristi tọwọ́ mi ṣe, láti mú kí àwọn tí wọn kì í ṣe Juu lè gbọ́ràn sí Ọlọrun. Mo ṣe àwọn nǹkan wọnyi nípa ọ̀rọ̀ ati ìṣe mi, pẹlu àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ẹ̀mí fún mi lágbára láti ṣe. Àyọrísí èyí ni pé láti Jerusalẹmu títí dé Iliriku ni mo ti waasu ìyìn rere Kristi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Olukuluku wa níláti máa ṣe ohun tí yóo tẹ́ ẹnìkejì rẹ̀ lọ́rùn fún ire rẹ̀ ati fún ìdàgbàsókè rẹ̀. Kì í ṣe àníyàn mi ni láti lọ waasu ìyìn rere níbi tí wọ́n bá ti gbọ́ orúkọ Kristi, kí n má baà kọ́lé lórí ìpìlẹ̀ tí ẹlòmíràn ti fi lélẹ̀. Ṣugbọn àníyàn mi rí bí ọ̀rọ̀ tí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Àwọn ẹni tí kò gbọ́ nípa rẹ̀ rí, yóo rí i.Ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yóo yé àwọn tí kò gbúròó rẹ̀ rí.” Ìdí nìyí tí mo fi ní ìdènà nígbà pupọ láti wá sọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn nisinsinyii, mo ti parí iṣẹ́ mi ní gbogbo agbègbè yìí. Bí mo sì ti ní ìfẹ́ fún ọdún pupọ láti wá sọ́dọ̀ yín, mo lérò láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí. N óo yà sọ́dọ̀ yín nígbà tí mo bá ń kọjá lọ sí Spania. Ìrètí mi ni láti ri yín, kí ẹ lè ràn mí lọ́wọ́, kí n lè débẹ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ní anfaani láti dúró lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀. Ṣugbọn mò ń lọ sí Jerusalẹmu báyìí láti fi ẹ̀bùn tí wọ́n fi ranṣẹ sí àwọn onigbagbọ tí ó wà níbẹ̀ jíṣẹ́. Nítorí àwọn ìjọ Masedonia ati ti Akaya ti fi inú dídùn ṣe ọrẹ fún àwọn aláìní ninu àwọn onigbagbọ tí ó wà ní Jerusalẹmu. Wọ́n fi inú dídùn ṣe é, ó sì jẹ wọ́n lógún láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí bí àwọn tí kì í ṣe Juu ti pín ninu àwọn nǹkan ti ẹ̀mí ti àwọn onigbagbọ láti Jerusalẹmu, ó yẹ kí wọ́n kà á sí iṣẹ́ ìsìn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹlu ohun ìní wọn. Nítorí náà, nígbà tí mo bá parí ètò yìí, tí mo ti fi ọwọ́ ara mi fún wọn ní ohun tí a rí kójọ, n óo gba ọ̀dọ̀ yín kọjá sí Spania. Mo mọ̀ pé, nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín, n óo wá pẹlu ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibukun ti Kristi. Nítorí Kristi kò ṣe nǹkan tí ó tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Dípò bẹ́ẹ̀ ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, “Èmi ni ẹ̀gàn àwọn ẹni tí ó ń gàn ọ́ rẹ́ lára.” Ará, mo fi Oluwa wa Jesu Kristi ati ìfẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́ bẹ̀ yín pé, kí ẹ máa fi ìtara bá mi gbadura sí Ọlọrun pé kí á lè gbà mí lọ́wọ́ àwọn alaigbagbọ ní Judia, ati pé kí iṣẹ́ tí mò ń lọ ṣe ní Jerusalẹmu lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú àwọn onigbagbọ ibẹ̀. Èyí yóo jẹ́ kí n fi ayọ̀ wá sọ́dọ̀ yín, bí Ọlọrun bá fẹ́, tí ọkàn mi yóo fi balẹ̀ nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín. Kí Ọlọrun alaafia kí ó wà pẹlu gbogbo yín. Amin. Nítorí fún àtikọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ni a ṣe kọ ohunkohun tí a ti kọ tẹ́lẹ̀, ìdí rẹ̀ ni pé kí ìgboyà ati ìwúrí tí Ìwé Mímọ́ ń fún wa lè fún wa ní ìrètí. Kí Ọlọrun, tí ó ń fún wa ní ìrọ́jú ati ìwúrí, jẹ́ kí ẹ ní ọkàn kan náà sí ara yín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Kristi Jesu, kí ẹ fi inú kan ati ohùn kan yin Ọlọrun ati Baba Oluwa Jesu Kristi. Nítorí náà, ẹ fa ara yín mọ́ra gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà yín, kí á lè fi ògo fún Ọlọrun. Ohun tí mò ń sọ ni pé Kristi ti di iranṣẹ fún àwọn tí ó kọlà, láti mú òtítọ́ Ọlọrun ṣẹ, kí ó lè mú àwọn ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba-ńlá ṣẹ, ati láti jẹ́ kí àwọn tí kò kọlà lè yin Ọlọrun nítorí àánú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí èyí, n óo yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,n óo kọrin sí orúkọ rẹ.” Paulu Kí Ọpọlọpọ Eniyan ninu Ìjọ Romu. Mo fẹ́ kí ẹ gba Febe bí arabinrin wa, ẹni tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọ tí ó wà ní Kẹnkiria. Ẹ kí Apele, akikanju onigbagbọ. Ẹ kí àwọn ará ilé Arisitobulu. Ẹ kí Hẹrodioni ìbátan mi. Ẹ kí àwọn ará ilé Nakisu tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ. Ẹ kí Tirufina ati Tirufosa, àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ Oluwa. Ẹ kí Pasisi, arabinrin àyànfẹ́ tí ó ti ṣiṣẹ́ pupọ ninu Oluwa. Ẹ kí Rufọsi, àṣàyàn onigbagbọ ati ìyá rẹ̀ tí ó tún jẹ́ ìyá tèmi náà. Ẹ kí Asinkiritu, Filegọnta, Herime, Patiroba, Herima ati àwọn arakunrin tí ó wá pẹlu wọn. Ẹ kí Filologu ati Julia, Nerea ati arabinrin rẹ̀, ati Olimpa ati gbogbo àwọn onigbagbọ tí ó wà lọ́dọ̀ wọn. Ẹ rọ̀ mọ́ ara yín, kí ẹ sì kí ara yín pẹlu alaafia. Gbogbo ìjọ Kristi kí yín. Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín pé kí ẹ máa fura sí àwọn tí ó ń dá ìyapa sílẹ̀ ati àwọn tí ń múni ṣìnà, tí wọn ń ṣe àwọn nǹkan tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́, ẹ yẹra fún irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀. Nítorí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kì í ṣe iranṣẹ Oluwa wa Kristi, ikùn ara wọn ni wọ́n ń bọ. Wọn a máa fi ọ̀rọ̀ dídùn ati kí á máa pọ́n eniyan tan àwọn tí kò bá fura jẹ. Ìròyìn ti tàn ká ibi gbogbo pé ẹ dúró ṣinṣin ninu igbagbọ. Èyí mú inú mi dùn nítorí yín. Mo fẹ́ kí ẹ jẹ́ amòye ninu nǹkan rere, ṣugbọn kí ẹ jẹ́ òpè ní ti àwọn nǹkan burúkú. Ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀ ní orúkọ Kristi gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ onigbagbọ. Kí ẹ ràn án lọ́wọ́ ní ọ̀nàkọ́nà tí ó bá fẹ́; nítorí ó jẹ́ ẹni tí ó ran ọpọlọpọ eniyan ati èmi pàápàá lọ́wọ́. Kí Ọlọrun orísun alaafia mu yín ṣẹgun Satani ní kíákíá. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín. Timoti alábàáṣiṣẹ́ mi ki yín. Bẹ́ẹ̀ náà ni Lukiusi ati Jasoni ati Sosipata, àwọn ìbátan wa. Èmi Tatiu tí mò ń bá Paulu kọ ìwé yìí ki yín: Ẹ kú iṣẹ́ Oluwa. Gaiyu náà ki yín. Òun ni ó gbà mí lálejò bí ó ti gba gbogbo ìjọ lálejò. Erastu, akápò ìlú, ki yín. Kuatu arakunrin wa náà ki yín.[ Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu gbogbo yín. Amin.] Ògo ni fún ẹni tí ó lágbára láti mu yín dúró gbọningbọnin, gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere ati iwaasu nípa Jesu Kristi ti wí ati gẹ́gẹ́ bí àdììtú tí Ọlọrun dì láti ayérayé, ṣugbọn tí ó wá tú ní àkókò yìí. Ìwé àwọn wolii ni ó ṣe ìṣípayá ohun tí ó fara pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọrun ayérayé, pé kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́, kí wọ́n mọ̀, kí wọ́n sì gbà. Ògo ni fún Ọlọrun ọlọ́gbọ́n kanṣoṣo nípa Jesu Kristi títí laelae. Amin. Ẹ kí Pirisila ati Akuila, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ Kristi Jesu. Wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti gbà mí lọ́wọ́ ikú. Èmi nìkan kọ́ ni mo dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, gbogbo ìjọ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu náà dúpẹ́ pẹlu. Ẹ kí ìjọ tí ó wà ní ilé wọn náà.Ẹ kí Epenetu àyànfẹ́ mi, ẹni tí ó jẹ́ onigbagbọ kinni ní ilẹ̀ Esia. Ẹ kí Maria, ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pupọ láàrin yín. Ẹ kí Andironiku ati Junia, àwọn ìbátan mi tí a jọ wà lẹ́wọ̀n. Olókìkí ni wọ́n láàrin àwọn òjíṣẹ́ Kristi, wọ́n sì ti di onigbagbọ ṣiwaju mi. Ẹ kí Ampiliatu àyànfẹ́ mi ninu Oluwa. Ẹ kí Ubanu alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ Kristi ati Sitaku àyànfẹ́ mi. Ìdájọ́ Òdodo Tí Ọlọrun Ṣe. Kò sí àwáwí kankan fún ọ, ìwọ tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. Nǹkan gan-an tí ò ń torí rẹ̀ dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́ ni o fi ń dá ara rẹ lẹ́bi. Nítorí ìwọ náà tí ò ń dáni lẹ́jọ́ ń ṣe àwọn nǹkan gan-an tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́bi fún. Ṣugbọn yóo fi ògo, ọlá ati alaafia fún gbogbo àwọn tí ó ń ṣe rere. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ fún, lẹ́yìn náà yóo fún àwọn Giriki. Nítorí Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ láì lófin, láì lófin náà ni wọn yóo kú. Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ Òfin, tí wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀, òfin náà ni a óo fi ṣe ìdájọ́ wọn. Kì í ṣe àwọn tí wọ́n gbọ́ ohun tí Òfin sọ ni Ọlọrun ń dá láre, àwọn tí wọn ń ṣe ohun tí Òfin sọ ni. Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu tí kò mọ Òfin bá ń ṣe ohun tí Òfin sọ bí nǹkan àmútọ̀runwá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mọ Òfin, wọ́n di òfin fún ara wọn. Irú àwọn wọnyi fihàn pé a ti kọ iṣẹ́ ti Òfin sinu ọkàn wọn. Ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣiṣẹ́ ninu wọn: àwọn èrò oríṣìíríṣìí tí ó wà ninu wọn yóo máa dá wọn láre tabi kí ó máa dá wọn lẹ́bi, ní ọjọ́ tí Ọlọrun yóo rán Jesu láti ṣe ìdájọ́ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo tí ó wà ninu eniyan gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí mò ń waasu. Ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní Juu, o gbójú lé Òfin, o wá ń fọ́nnu pé o mọ Ọlọrun. O mọ ohun tí Ọlọrun fẹ́. O mọ àwọn ohun tí ó dára jù nítorí a ti fi Òfin kọ́ ọ. O dá ara rẹ lójú bí ẹni tí ó jẹ́ amọ̀nà fún àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn. Ṣugbọn a mọ̀ pé Ọlọrun ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi. O pe ara rẹ ní ẹni tí ó lè bá àwọn tí kò gbọ́n wí, olùkọ́ àwọn ọ̀dọ́, ẹni tí ó mọ àwọn nǹkan tí ó jẹ́ kókó ati òtítọ́ tí ó wà ninu Òfin. Ìwọ tí ò ń kọ́ ẹlòmíràn, ṣé o kò ní kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ò ń waasu pé kí eniyan má jalè, ṣé ìwọ náà kì í jalè? Ìwọ tí o sọ pé kí eniyan má ṣe àgbèrè, ṣé ìwọ náà kì í ṣe àgbèrè? Ìwọ tí o kórìíra oriṣa, ṣé o kì í ja ilé ìbọ̀rìṣà lólè? Ìwọ tí ò ń fọ́nnu pé o mọ Òfin, ṣé o kì í mú ẹ̀gàn bá Ọlọrun nípa rírú Òfin? Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Orúkọ Ọlọrun di ohun ìṣáátá láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu nítorí yín.” Ilà tí o kọ ní anfaani, bí o bá ń pa Òfin mọ́. Ṣugbọn tí o bá rú Òfin, bí àìkọlà ni ìkọlà rẹ rí. Ǹjẹ́ bí aláìkọlà bá ń pa àwọn ìlànà òdodo tí ó wà ninu Òfin mọ́, a kò ha ní ka àìkọlà rẹ̀ sí ìkọlà? Ẹni tí a bí ní aláìkọlà tí ó ń pa Òfin mọ́, ó mú ìtìjú bá ìwọ tí a kọ Òfin sílẹ̀ fún, tí o kọlà, ṣugbọn sibẹ tí o jẹ́ arúfin. Kì í ṣe nǹkan ti òde ara ni eniyan fi ń jẹ́ Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìkọlà kì í ṣe kí á fabẹ gé ara. Ṣugbọn láti jẹ́ Juu tòótọ́ jẹ́ ohun àtinúwá; ìkọlà jẹ́ nǹkan ti ọkàn. Nǹkan ti ẹ̀mí ni, kì í ṣe ti inú ìwé. Ìyìn irú ẹni bẹ́ẹ̀ wà lọ́dọ̀ Ọlọrun, kì í ṣe ọ̀dọ̀ eniyan. Ìwọ tí ò ń dá àwọn ẹlòmíràn tí ó ń ṣe nǹkan wọnyi lẹ́jọ́, tí ìwọ alára sì ń ṣe nǹkankan náà, ṣé o wá rò pé ìwọ óo bọ́ ninu ìdájọ́ Ọlọrun ni? Àbí o fi ojú tẹmbẹlu ọpọlọpọ oore Ọlọrun ni, ati ìfaradà rẹ̀ ati sùúrù rẹ̀? O kò mọ̀ pé kí o lè ronupiwada ni gbogbo oore tí Ọlọrun ń ṣe, Ṣugbọn nípa oríkunkun ati agídí ọkàn rẹ, ò ń fi ibinu Ọlọrun pamọ́ fún ara rẹ títí di ọjọ́ ibinu ati ìgbà tí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun yóo dé. Ọlọrun yóo san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀; yóo fi ìyè ainipẹkun fún àwọn tí ń fi sùúrù ṣe iṣẹ́ rere nípa lílépa àwọn nǹkan tí ó lógo, tí ó sì lọ́lá, àwọn nǹkan tí kò lè bàjẹ́. Ṣugbọn ní ti àwọn tí ó jẹ́ pé ti ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, ati àwọn tí kò gba òtítọ́, àwọn tí wọ́n gba ohun burúkú, Ọlọrun yóo fi ibinu ati ìrúnú rẹ̀ hàn wọ́n; yóo mú ìpọ́njú ati ìṣòro bá gbogbo àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ ibi. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ kàn, lẹ́yìn náà àwọn Giriki. Kò Sí Olódodo kan. Ọ̀nà wo wá ni àwọn Juu fi sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ? Kí ni anfaani ìkọlà? Ó wà ní àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ pé, “Kò sí ẹnìkan tí ó jẹ́ olódodo; kò sí ẹnìkankan. Kò sí ẹni tí òye yé,kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọrun. Gbogbo wọn ti yapa kúrò lójú ọ̀nà,gbogbo wọn kò níláárí mọ́,kò sí ẹni tí ó ń ṣe rere,kò sí ẹnìkan. Ibojì tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀nà ọ̀fun wọn, ẹ̀tàn kún ẹnu wọn;oró paramọ́lẹ̀ wà létè wọn; ẹnu wọn kún fún èpè ati ọ̀rọ̀ burúkú. Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀nà jamba ati òṣì ni wọ́n ń rìn. Wọn kò mọ ọ̀nà alaafia. Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ní ọkàn wọn.” A mọ̀ pé ohunkohun tí Òfin bá wí, ó wà fún àwọn tí ó mọ Òfin ni, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rí àwáwí wí, kí gbogbo aráyé lè wà lábẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun. Ó pọ̀ pupọ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. Ekinni, àwọn Juu ni Ọlọrun fún ní ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, bí a bá mú Òfin tí a fi díwọ̀n iṣẹ́ ọmọ eniyan, kò sí ẹ̀dá kan tí a óo dá láre níwájú Ọlọrun. Nítorí òfin níí mú kí eniyan mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre ti hàn láìsí Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ ti Òfin ati ti àwọn wolii Ọlọrun jẹ́rìí sí i. Gbogbo àwọn tí ó bá gba Jesu gbọ́ yóo yege lọ́dọ̀ Ọlọrun láìsí ìyàtọ̀ kan. Nítorí gbogbo eniyan ló ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọrun. Gbogbo wọn ni Ọlọrun ti ṣe lóore: ó dá wọn láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa ìràpadà tí Kristi Jesu ṣe. Jesu yìí ni Ọlọrun fi ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́, nípa ikú rẹ̀. Èyí ni láti fi ọ̀nà tí Ọlọrun yóo fi dá eniyan láre hàn, nítorí pé ó fi ojú fo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dá, nípa ìyọ́nú rẹ̀, kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn ní àkókò yìí, kí ó lè hàn pé olódodo ni òun, ati pé òun ń dá ẹni tí ó bá gba Jesu gbọ́ láre. Ààyè ìgbéraga dà? Kò sí rárá. Nípa irú ìlànà wo ni kò fi sí mọ́? Nípa iṣẹ́ Òfin ni bí? Rárá o! Nípa ìlànà ti igbagbọ ni. Nítorí ohun tí a rí ni pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun ń dá eniyan láre, kì í ṣe nípa pípa Òfin mọ́. Àbí ti àwọn Juu nìkan ni Ọlọrun, kì í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù? Dájúdájú Ọlọrun àwọn Juu ati ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ni. Ẹ lè wá sọ pé, “Anfaani wo ni ó wà ninu èyí nígbà tí àwọn mìíràn ninu wọn kò gbàgbọ́? Ǹjẹ́ aigbagbọ wọn kò sọ ìṣòtítọ́ Ọlọrun di òtúbáńtẹ́?” Nígbà tí ó jẹ́ pé Ọlọrun kanṣoṣo ni ó wà, òun ni ó sì ń dá àwọn tí ó kọlà láre nípa igbagbọ, tí ó tún ń dá àwọn tí kò kọlà láre nípa igbagbọ bákan náà. Ṣé Òfin wá di òtúbáńtẹ́ nítorí igbagbọ ni? Rárá o! A túbọ̀ fi ìdí Òfin múlẹ̀ ni. Rárá o! Ọlọrun níláti jẹ́ olóòótọ́ bí gbogbo eniyan bá tilẹ̀ di onírọ́. Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Kí ìwọ Ọlọrun lè jẹ́ olódodo ninu ọ̀rọ̀ rẹ,kí o lè borí nígbà tí wọ́n bá pè ọ́ lẹ́jọ́.” Bí aiṣododo wa bá mú kí òdodo Ọlọrun fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ni kí á wá wí? Ṣé Ọlọrun kò ṣe ẹ̀tọ́ láti bínú sí wa ni? (Mò ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé eniyan ni Ọlọrun.) Rárá o! Bí Ọlọrun kò bá ní ẹ̀tọ́ láti bínú, báwo ni yóo ṣe wá ṣe ìdájọ́ aráyé? Bí aiṣotitọ mi bá mú kí ògo òtítọ́ Ọlọrun túbọ̀ hàn, kí ni ṣe tí a tún fi ń dá mi lẹ́bi bí ẹlẹ́ṣẹ̀? Ṣé, “Kí á kúkú máa ṣe ibi kí rere lè ti ibẹ̀ jáde?” Bí àwọn onísọkúsọ kan ti ń sọ pé à ń sọ. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yẹ fún ìdálẹ́bi. Kí ni kí á rí dìmú ninu ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé àwa Juu sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ ni? Rárá o! Nítorí a ti wí ṣáájú pé ati Juu ati Giriki, gbogbo wọn ni ó wà ní ìkáwọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Àpẹẹrẹ Abrahamu. Kí ni kí á wí nípa Abrahamu baba-ńlá wa nípa ti ara? Kí ni ìrírí rẹ̀? Ipò wo ni ó wà tí Ọlọrun fi kà á sí ẹni rere: lẹ́yìn tí ó ti kọlà ni tabi kí ó tó kọlà? Kì í ṣe lẹ́yìn tí ó ti kọlà, kí ó tó kọlà ni. Ó gba àmì ìkọlà bí ẹ̀rí iṣẹ́ rere nípa igbagbọ tí ó ní nígbà tí kò ì tíì kọlà. Nítorí èyí, ó di baba fún gbogbo àwọn tí ó ní igbagbọ láì kọlà, kí Ọlọrun lè kà wọ́n sí ẹni rere; ó sì di baba fún àwọn tí ó kọlà ṣugbọn tí wọn kò gbẹ́kẹ̀lé ilà tí wọ́n kọ, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní irú ọ̀nà igbagbọ tí baba wa Abrahamu ní kí ó tó kọlà. Nítorí kì í ṣe nítorí pé Abrahamu pa Òfin mọ́ ni Ọlọrun fi ṣe ìlérí fún òun ati ìran rẹ̀ pé yóo jogún ayé; nítorí ó gba Ọlọrun gbọ́ ni, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ń tẹ̀lé ètò Òfin ni yóo jogún ìlérí Ọlọrun, a jẹ́ pé ọ̀ràn àwọn tí ó dúró lórí igbagbọ di òfo, ìlérí Ọlọrun sì di òtúbáńtẹ́. Nítorí òfin ni ó ń mú ibinu Ọlọrun wá. Ṣugbọn níbi tí kò bá sí òfin, kò sí ẹ̀ṣẹ̀. Ìdí nìyí tí ìlérí náà fi jẹ́ ti igbagbọ, kí ó lè jẹ́ ọ̀fẹ́, kí ó sì lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún gbogbo ọmọ Abrahamu. Kì í ṣe fún àwọn tí ó gba ètò ti Òfin nìkan, bíkòṣe fún ẹni tí ó bá ní irú igbagbọ tí Abrahamu ẹni tí ó jẹ́ baba fún gbogbo wa ní. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Mo ti yàn ọ́ láti di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.” Níwájú Ọlọrun ni Abrahamu wà nígbà tí ó gba ìlérí yìí, níwájú Ọlọrun tí ó gbẹ́kẹ̀lé, Ọlọrun tí ó ń sọ òkú di alààyè, Ọlọrun tí ó ń pe àwọn ohun tí kò ì tíì sí jáde bí ẹni pé wọ́n wá. Abrahamu retí títí, ó gbàgbọ́ pé òun yóo di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti wí, pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ yóo rí.” Igbagbọ rẹ̀ kò yẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ro ti ara rẹ̀ tí ó ti di òkú tán, (nítorí ó ti tó ẹni ọgọrun-un ọdún) ó tún ro ti Sara tí ó yàgàn. Bí ó bá jẹ́ pé nítorí ohun tí ó ṣe ni Ọlọrun fi dá a láre, ìwọ̀nba ni ohun tí ó lè fi ṣe ìgbéraga. Ṣugbọn kò lè fọ́nnu níwájú Ọlọrun. Kò fi aigbagbọ ṣiyèméjì sí ìlérí Ọlọrun. Kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni igbagbọ rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i, ó fi ògo fún Ọlọrun nítorí pé ó dá a lójú pé ẹni tí ó ṣe ìlérí lè mú un ṣẹ. Ìdí rẹ̀ nìyí tí Ọlọrun fi ka igbagbọ rẹ̀ sí iṣẹ́ rere fún un. Ṣugbọn kì í ṣe nípa òun nìkan ṣoṣo ni a kọ ọ́ pé a ka igbagbọ sí iṣẹ́ rere. A kọ ọ́ nítorí ti àwa náà tí a óo kà sí ẹni rere, gbogbo àwa tí a ní igbagbọ ninu ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde kúrò ninu òkú, ẹni tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde fún ìdáláre wa. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ni pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere.” A kò lè pe èrè tí òṣìṣẹ́ bá gbà ní ẹ̀bùn; ẹ̀tọ́ rẹ̀ ni. Ṣugbọn ẹni tí kò ṣe nǹkankan, ṣugbọn tí ó ṣá ní igbagbọ sí ẹni tí ó ń dá ẹni tí kò yẹ láre, Ọlọrun kà á sí ẹni rere nípa igbagbọ rẹ̀. Dafidi náà sọ̀rọ̀ nípa oríire ẹni tí Ọlọrun kà sí ẹni rere, láìwo iṣẹ́ tí ó ṣe. Ó ní, “Ẹni tí Ọlọrun bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì, tí Ọlọrun bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó ṣoríire. Ẹni tí Oluwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn sì ṣoríire.” Ṣé ẹni tí ó kọlà nìkan ni ó ṣoríire ni, tabi ati ẹni tí kò kọlà náà? Ohun tí a sọ ni pé, “Ọlọrun ka igbagbọ sí iṣẹ́ rere fún Abrahamu.” Àyọrísí Ìdáláre. Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nítorí pé a gba Ọlọrun gbọ́, kò sí ìjà mọ́ láàrin àwa ati Ọlọrun: Jesu Kristi Oluwa wa ti parí ìjà. Bí ikú Ọmọ Ọlọrun bá sọ àwa tí a jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun di ọ̀rẹ́ rẹ̀, nígbà yìí tí a wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun tán, ajinde ọmọ rẹ̀ yóo gbà wá là ju tàtẹ̀yìnwá lọ. Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣugbọn à ń yọ̀ ninu Ọlọrun nítorí ohun tí ó ṣe nípa Oluwa wa Jesu Kristi, ẹni tí ó sọ wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun ní àkókò yìí. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe ti ipasẹ̀ ẹnìkan wọ inú ayé, tí ikú sì ti ipasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọlé, bẹ́ẹ̀ náà ni ikú ṣe ran gbogbo eniyan, nítorí pé gbogbo eniyan ni ó ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ṣiwaju Òfin dáyé, bẹ́ẹ̀ bí kò bá sí òfin a kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí eniyan lọ́rùn. Ṣugbọn ikú ti jọba ní tirẹ̀ láti ìgbà Adamu títí dé ìgbà Mose, àwọn tí kò tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ nípa rírú òfin bíi Adamu, pẹlu àwọn tí ikú pa, Adamu tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ irú ẹni tó ń bọ̀. Kì í ṣe bí eniyan ṣe rú òfin tó ni Ọlọrun fi ń wọn ìfẹ́ ati àánú rẹ̀. Bí gbogbo eniyan bá jogún ikú nítorí aṣemáṣe ẹnìkan, oore-ọ̀fẹ́ ati àánú tí Ọlọrun fún gbogbo eniyan láti ọwọ́ ẹnìkan, àní Jesu Kristi, ó pọ̀ pupọ; ó pọ̀ ju ogún ikú lọ. Kì í ṣe ẹnìkan tí ó dẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọrun ń wò kí ó tó ta àwọn eniyan lọ́rẹ. Ẹnìkan ló fa ìdájọ́ Ọlọrun. Ẹ̀bi ni a sì rí gbà ninu rẹ̀. Ṣugbọn àánú tí Ọlọrun fún wa dípò ọpọlọpọ aṣemáṣe wa, ìdáláre ni ó yọrí sí. Bí ikú bá torí òfin tí ẹnìkan rú jọba lé wa lórí, àwọn tí ó ti gba ibukun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí wọ́n sì gba ìdáláre lọ́fẹ̀ẹ́, yóo ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ: wọn óo jọba, wọn óo sì yè pẹlu àṣẹ ẹnìkan, Jesu Kristi. Nítorí náà, bí òfin tí ẹnìkan rú ṣe ti gbogbo ọmọ aráyé sinu ìdájọ́ ikú, bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ rere ẹnìkan yóo yọ gbogbo ọmọ aráyé ninu ìdájọ́ ikú sí ìyè. Bí a ti sọ gbogbo eniyan di ẹlẹ́ṣẹ̀ nítorí àìgbọràn ẹnìkan, bẹ́ẹ̀ náà ni a óo torí ìgbọràn ẹnìkan dá gbogbo eniyan láre. Ọpẹ́lọpẹ́ rẹ̀ ni a fi rí ọ̀nà gbà dé ipò oore-ọ̀fẹ́ tí a wà ninu rẹ̀ yìí. A wá ń yọ̀ ninu ògo Ọlọrun tí à ń retí. Ọ̀nà ẹ̀bùrú ni òfin gbà wọlé, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè pọ̀ jantirẹrẹ. Níbi tí ẹ̀ṣẹ̀ bá sì ti pọ̀, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun a máa pọ̀ ju bí ẹ̀ṣẹ̀ ti pọ̀ tó lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ikú ṣe sọ ẹ̀ṣẹ̀ di ọba, bẹ́ẹ̀ ni ìdáláre náà ń fi oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jọba, ó sì mú wa wọnú ìyè ainipẹkun nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa. Èyí nìkan kọ́. A tún ń fi àwọn ìṣòro wa ṣe ọlá, nítorí a mọ̀ pé àyọrísí ìṣòro ni ìfaradà; àyọrísí ìfaradà ni ìyege ìdánwò; àyọrísí ìyege ìdánwò ni ìrètí. Ìrètí irú èyí kì í ṣe ohun tí yóo dójú tì wá, nítorí a ti tú ìfẹ́ Ọlọrun dà sí wa lọ́kàn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fún wa. Nítorí nígbà tí a jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó wọ̀, Kristi kú fún àwa tí kò ka Ọlọrun sí. Bóyá ni a lè rí ẹni tí yóo fẹ́ kú fún olódodo. Ṣugbọn ó ṣeéṣe kí á rí ẹni tí yóo ní ìgboyà láti kú fún eniyan rere. Ṣugbọn Ọlọrun fihàn wá pé òun fẹ́ràn wa ní ti pé nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa. Bí ó bá lè kú fún wa nígbà tí a sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, nisinsinyii tí Ọlọrun ti dá wa láre nítorí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, a óo sì torí rẹ̀ gbà wá kúrò ninu ibinu tí ń bọ̀. Ikú sí Ẹ̀ṣẹ̀, Ìyè ninu Kristi. Kí ni kí á wí nígbà náà? Ṣé kí a túbọ̀ máa dẹ́ṣẹ̀ kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun lè máa pọ̀ sí i? Kíkú tí ó kú jẹ́ pé ó ti kú ikú tí ó níláti kú lẹ́ẹ̀kan; yíyè tí ó yè, ó yè fún ògo Ọlọrun. Bákan náà ni kí ẹ ka ara yín bí ẹni tí ó ti kú ní ayé ẹ̀ṣẹ̀, tí ó tún wà láàyè pẹlu Ọlọrun ninu Kristi. Nítorí èyí, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ tún rí ààyè jọba ninu ara yín tí ẹ óo fi máa fààyè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara. Ẹ má sì gbé ara yín sílẹ̀ bí ohun èèlò fún ẹ̀ṣẹ̀. Dípò èyí, ẹ lo ara yín fún iṣẹ́ òdodo, kí ẹ sì fi í fún Ọlọrun, ẹni tí ó lè sọ òkú dààyè. Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀gá yín, nítorí ẹ kò sí lábẹ́ Òfin; abẹ́ oore-ọ̀fẹ́ ni ẹ wà. Kí ló wá kù kí á ṣe? Ṣé kí á máa dá ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé a kò sí lábẹ́ òfin, abẹ́ oore-ọ̀fẹ́ ni a wà. Ká má rí i. Ẹ kò mọ̀ pé ẹrú ẹni tí ẹ bá ń gbọ́ràn sí lẹ́nu lẹ jẹ́, ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fara yín ṣẹrú fún, tí ẹ sì ń jíṣẹ́ fún? Ẹ lè fi ara yín ṣẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀, kí ó fikú san án fun yín; ẹ sì lè fìgbọràn ṣọ̀gá fún ara yín, kí ó sì fun yín ní ìdáláre. Ọpẹ́ ni fỌlọrun, nítorí pé ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣẹrú ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ti wá ń fi tọkàntọkàn gba irú ẹ̀kọ́ tí a gbé kalẹ̀ níwájú yín. A ti tu yín sílẹ̀ ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀ṣẹ̀, ẹ ti di ẹrú iṣẹ́ rere. Mò ń fọ èdè tí ó lè yé eniyan, nítorí ọgbọ́n yín kò ì tíì kọjá ohun tí a lè fi ojú rí. Bí ẹ ti gbé ara yín fún ìwà èérí ati ìwà tinú-mi-ni-n-óo-ṣe, tí a sì fi yín sílẹ̀ kí ẹ máa ṣe bí ó ti wù yín, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ wá fi ara yín jìn fún iṣẹ́ rere, kí ẹ sìn ín fún iṣẹ́ mímọ́. Kí á má rí i. Báwo ni àwa tí a ti fi ayé ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, ṣe tún lè máa gbé inú ẹ̀ṣẹ̀? Nígbà tí ẹ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, kò sí ohun tí ẹ bá iṣẹ́ rere dàpọ̀. Èrè wo ni ẹ rí gbà lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, àfi ohun tí ń tì yín lójú nisinsinyii? Ikú ni irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí. Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ ti bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, tí ẹ ti di ẹrú Ọlọrun, èrè tí ẹ óo máa rí, ti ohun mímọ́ ni. Ìyè ainipẹkun ni yóo sì yọrí sí. Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìyè ainipẹkun pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa. Àbí ẹ kò mọ̀ pé gbogbo àwa tí a ti rì bọmi lórúkọ Jesu a ti kú bí Jesu ti kú? Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jọ sin wá pọ̀ nígbà tí wọ́n rì wá bọmi, tí wọ́n sọ wá di òkú, kí àwa náà lè máa gbé ìgbé-ayé titun gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun baba ògo ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú. Bí a bá sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu Jesu ninu ikú, a óo sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu rẹ̀ ninu ajinde. Ẹ jẹ́ kí òye yìí yé wa: a ti kan ẹni àtijọ́ tí àwọn eniyan mọ̀ wá sí mọ́ agbelebu pẹlu Jesu, kí ẹran-ara tí eniyan fi ń dẹ́ṣẹ̀ lè di òkú, kí á lè bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí ẹni tí ó ti kú ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Bí a bá jọ bá Jesu kú, a ní igbagbọ pé a óo jọ bá Jesu yè. A mọ̀ pé Kristi tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kò tún ní kú mọ́; ikú kò sì lè jọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́. Àpẹẹrẹ láti inú Igbeyawo. Ẹ̀yin ará mi, ohun tí mò ń wí yìí kò ṣe àjèjì si yín (nítorí ẹ̀yin náà mọ òfin), pé òfin de eniyan níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láàyè nìkan. ni mo bá kú. Òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá, ni ó wá di ọ̀ràn ikú fún mi. Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ rí ohun dìrọ̀ mọ́ ninu òfin, ó tàn mí jẹ, ó sì pa mí kú. Dájú, ohun mímọ́ ni Òfin, àwọn àṣẹ tí ó wà ninu rẹ̀ náà sì jẹ́ ohun mímọ́, ohun tí ó tọ́, tí ó sì dára. Ǹjẹ́ ohun tí ó dára yìí ni ó ṣe ikú pa mí? Rárá o! Ẹ̀ṣẹ̀ níí ṣekú pani. Kí ẹ̀ṣẹ̀ lè fara rẹ̀ hàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó lo ohun tí ó dára láti pa mí kú, báyìí, ó hàn gbangba pé ibi gan-an ni ẹ̀ṣẹ̀ í ṣe, nítorí ó kó sábẹ́ òfin láti ṣe ibi. Àwa mọ̀ dájú pé Òfin jẹ́ nǹkan ti Ẹ̀mí. Ṣugbọn èmi jẹ́ eniyan ẹlẹ́ran-ara, tí a ti tà lẹ́rú fún ẹ̀ṣẹ̀. Ìwà mi kò yé èmi alára; nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan tí mo bá fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, àwọn nǹkan tí mo kórìíra gan-an ni mò ń ṣe. Níwọ̀n ìgbà tí mo bá ń ṣe àwọn nǹkan tí n kò fẹ́, mò ń jẹ́rìí sí i pé Òfin jẹ́ ohun tí ó dára. Wàyí ò, ó já sí pé kì í ṣe èmi alára ni mò ń hùwà bẹ́ẹ̀, bíkòṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. Mo mọ̀ dájú pé, kò sí agbára kan ninu èmi eniyan ẹlẹ́ran-ara, láti ṣe rere, n kò lágbára láti ṣe é. Nítorí kì í ṣe nǹkan rere tí mo fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, ṣugbọn àwọn nǹkan burúkú tí n kò fẹ́, ni mò ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, òfin igbeyawo de abilekọ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá kú, òfin tí ó de obinrin náà mọ́ ọkọ rẹ̀ kò ṣiṣẹ́ mọ́. Tí ó bá wá jẹ́ pé àwọn nǹkan tí n kò fẹ́ ni mò ń ṣe, a jẹ́ pé kì í ṣe èmi ni mò ń ṣe é, bíkòṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. Mo wá rí i wàyí pé, ó ti di bárakú fún mi, pé nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe rere, àwọn nǹkan burúkú ni ó yá sí mi lọ́wọ́. Mo yọ̀ gidigidi ninu ọkàn mi pé Ọlọrun ṣe òfin. Ṣugbọn bí mo ti wòye, àwọn ẹ̀yà ara mi ń tọ ọ̀nà mìíràn, tí ó lòdì sí ọ̀nà tí ọkàn mi fẹ́, ọ̀nà òdì yìí ni ó gbé mi sinu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu àwọn ẹ̀yà ara mi. Irú ẹ̀dá wo tilẹ̀ ni tèmi yìí! Ta ni yóo gbà mí lọ́wọ́ ara tí ó fẹ́ ṣekú pa mí yìí? Háà! Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun! Òun nìkan ló lè gbà mí là nípa Jesu Kristi Oluwa wa.Bí ọ̀rọ̀ ara mi ti wá rí nìyí: ní ìdà kinni, mò ń tẹ̀lé ìlànà òfin Ọlọrun ninu àwọn èrò ọkàn mi: ní ìdà keji ẹ̀wẹ̀, èmi yìí kan náà, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara, mo tún ń tọ ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀. Wàyí ò, bí obinrin náà bá lọ bá ọkunrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè, alágbèrè ni a óo pè é. Ṣugbọn tí ọkọ rẹ̀ bá ti kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin igbeyawo, kì í ṣe àgbèrè mọ́, bí ó bá lọ fẹ́ ọkọ mìíràn. Bẹ́ẹ̀ náà ni, ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin náà ti kú ní ti Òfin, nígbà tí ẹ di ara kan náà pẹlu Kristi. Ẹ ti ní ọkọ mìíràn, àní, ẹni tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kí á lè sin Ọlọrun lọ́nà tí yóo yọrí sí rere. Tẹ́lẹ̀ rí, nígbà tí a ti ń ṣe ìfẹ́ inú wa bí ẹlẹ́ran-ara, èrò ọkàn wa a máa fà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Òfin dá wa lẹ́kun rẹ̀, láti tì wá sí ohun tí àyọrísí rẹ̀ jẹ́ ikú. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti bọ́ kúrò lábẹ́ Òfin. A ti kú sí ohun tí ó dè wá. Báyìí, a kò sin Ọlọrun lọ́nà àtijọ́ mọ́, àní lọ́nà ti Òfin àkọsílẹ̀, ṣugbọn ní ọ̀nà titun ti Ẹ̀mí. Kí ni kí á wá wí wàyí ò? Ṣé Òfin wá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Rárá o! Ṣugbọn ṣá, èmi kì bá tí mọ ẹ̀ṣẹ̀ bí Òfin kò bá fi í hàn mí. Bí àpẹẹrẹ, ǹ bá tí mọ ojúkòkòrò bí Òfin kò bá sọ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.” Àṣẹ yìí ni ẹ̀ṣẹ̀ rí dìrọ̀ mọ́ láti fi ṣiṣẹ́. Ó ń fi èrò oríṣìíríṣìí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí mi lọ́kàn. Bí a bá mú òfin kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ di òkú. Nígbà kan rí mò ń gbé ìgbésí-ayé mi láìsí òfin. Ṣugbọn nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ yọjú pẹlu, Ìgbésí-Ayé Onigbagbọ ninu Ẹ̀mí. Nisinsinyii, kò sí ìdálẹ́bi kan mọ́ fún àwọn tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Ṣugbọn bí Kristi bá ń gbé inú yín, bí ara yín yóo tilẹ̀ kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀, sibẹ ẹ̀mí yín yóo wà láàyè nítorí pé Ọlọrun ti da yín láre. Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Ọlọrun, ẹni tí ó jí Jesu dìde kúrò ninu òkú, bá ń gbé inú yín, òun náà tí ó jí Kristi dìde kúrò ninu òkú yóo sọ ara yín, tí yóo kú, di alààyè nípa Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó ń gbé inú yín. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kò sí ohunkohun mọ́ tí ó mú wa ní túlààsì pé kí á máa hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí. Nítorí bí ẹ bá hùwà bí àwọn tí ẹran-ara ń darí, kíkú ni ẹ óo kú dandan. Ṣugbọn tí ẹ bá ń rìn lọ́nà ti Ẹ̀mí, tí ẹ kò sì hu ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ẹ óo yè. Nítorí àwọn tí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń darí ni ọmọ Ọlọrun. Ẹ̀mí tí Ọlọrun fun yín kì í ṣe èyí tí yóo tún sọ yín di ẹrú, tí yóo sì máa mu yín bẹ̀rù. Ṣugbọn Ẹ̀mí tí ó sọ yín di ọmọ ni ẹ gbà. Ẹ̀mí yìí náà ni ó jẹ́ kí á lè máa ké pe Ọlọrun pé, “Baba! Baba wa!” Ẹ̀mí kan náà ní ń sọ sí wa lọ́kàn pé ọmọ Ọlọrun ni wá. Wàyí ò, tí a bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá. Tí a bá sì jẹ́ ajogún, a jẹ́ pé àwa pẹlu Kristi ni a óo jọ jogún pọ̀, bí a bá bá Kristi jìyà, a óo bá a gba iyì pẹlu. Mo wòye pé a kò lè fi ìyà ayé yìí wé ọlá tí Ọlọrun yóo dá wa ní ayé tí ń bọ̀ wá. Nítorí gbogbo ẹ̀dá ayé ló ń fi ìwàǹwára nàgà, tí wọn ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo fi àwọn tíí ṣe ọmọ rẹ̀ hàn. Ìdí ni pé, agbára Ẹ̀mí, tí ó ń fi ìyè fún àwọn tí ń bá Kristi gbé, ti dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ati kúrò lábẹ́ àṣẹ ikú. Nítorí pé gbogbo ẹ̀dá ayé ló ti pasán, kì í ṣe pé ẹ̀dá ayé fúnra wọn ni wọ́n fẹ́ pasán, ṣugbọn bẹ́ẹ̀ ni ó wu Ẹlẹ́dàá láti yàn án. Sibẹ ìrètí ń bẹ pé: ẹ̀dá ayé pàápàá yóo bọ́ lóko ẹrú, kúrò ninu ipò ìdíbàjẹ́, yóo sì pín ninu ọlá àwọn ọmọ Ọlọrun. Àwa náà rí i pé, títí di òní olónìí, gbogbo ẹ̀dá ayé ni wọ́n ń jẹ̀rora, tí wọ́n sì ń rọbí bí aboyún. Ṣugbọn kì í ṣe ẹ̀dá ayé nìkan ló ń jẹ̀rora. Àní sẹ́, àwa fúnra wa, tí a ti rí Ẹ̀mí Ọlọrun gbà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn rẹ̀ àkọ́kọ́, à ń jẹ̀rora lọ́kàn wa, bí a ti ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo pè wá lọ́mọ rẹ̀, tí yóo sì dá gbogbo ara wa nídè. Nítorí ti ìrètí yìí ni a fi gbà wá là. Ṣebí ohun tí a bá ti fojú rí ti kúrò ní ohun tí à ń retí. Àbí, ta ni í tún máa ń retí ohun tí ó bá ti rí? Ṣugbọn nígbà tí a bá ń retí ohun tí a kò ì tíì fojú rí, dídúró ni à á dúró dè é pẹlu ìfaradà títí yóo fi tẹ̀ wá lọ́wọ́. Bákan náà, Ẹ̀mí tún ń ràn wá lọ́wọ́ ninu àìlera wa. Nítorí a kò mọ ohun tí ó tọ́ tí à bá máa gbadura fún. Ṣugbọn Ẹ̀mí fúnrarẹ̀ a máa bẹ̀bẹ̀ fún wa lọ́dọ̀ Ọlọrun lọ́nà tí a kò lè fi ẹnu sọ. Ọlọrun, Olùmọ̀ràn ọkàn, mọ èrò tí ó wà lọ́kàn Ẹ̀mí, nítorí Ẹ̀mí níí máa bẹ̀bẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun bí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti fẹ́. Àwa mọ̀ dájú pé Ọlọrun a máa mú kí ohun gbogbo yọrí sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀, àwọn tí ó ti pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀ láti ayébáyé. Nítorí àwọn tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwọn ni ó yà sọ́tọ̀ kí wọ́n lè dàbí Ọmọ rẹ̀, kí Ọmọ rẹ̀ yìí lè jẹ́ àkọ́bí láàrin ọpọlọpọ mọ̀lẹ́bí. Èyí jẹ́ nǹkan tí kò ṣe é ṣe lábẹ́ Òfin, nítorí eniyan kò lè ṣàì dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe é, nígbà tí ó dá ẹ̀bi ikú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu ẹ̀yà ara eniyan. Àní sẹ́, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí eniyan ẹlẹ́ṣẹ̀ láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́. Àwọn tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwọn ni ó pè. Àwọn tí ó pè ni ó dá láre. Àwọn tí ó sì dá láre ni ó dá lọ́lá. Kí ni kí á wá wí sí gbogbo nǹkan wọnyi? Bí Ọlọrun bá wà lẹ́yìn wa, ta ni lè lòdì sí wa? Ọlọrun, tí kò dá Ọmọ rẹ̀ sí, ṣugbọn tí ó yọ̀ǹda rẹ̀ nítorí gbogbo wa, báwo ni kò ṣe ní fún wa ní ohun gbogbo pẹlu rẹ̀? Ta ni yóo fi ẹ̀sùn kan kan àwọn ẹni tí Ọlọrun ti yàn? Ṣé Ọlọrun ni, òun tí ó dá wọn láre? Àbí ta ni yóo dá wọn lẹ́bi? Dájúdájú, kò lè jẹ́ Kristi, ẹni tí ó kú, àní sẹ́ ẹni tí a jí dìde kúrò ninu òkú, tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, tí ó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa. Ta ni yóo yà wá kúrò ninu ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni bí, tabi ìṣòro, tabi inúnibíni, tabi ìyàn, tabi òṣì, tabi ewu, tabi idà? Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí rẹ a wà ninu ewu ikú lojoojumọ,wọ́n sì ṣe wá bí aguntan tí wọ́n fẹ́ lọ pa.” Ṣugbọn ninu gbogbo ìrírí wọnyi, a ti borí gbogbo ìṣòro nípa agbára ẹni tí ó fẹ́ràn wa. Nítorí ó dá mi lójú pé, kò sí ohunkohun–ìbáà ṣe ikú tabi ìyè, ìbáà ṣe àwọn angẹli tabi àwọn irúnmọlẹ̀, tabi àwọn ohun ayé òde òní tabi àwọn ti ayé tí ó ń bọ̀, yálà àwọn àlùjọ̀nnú ojú-ọ̀run tabi àwọn ẹbọra inú ilẹ̀; lọ́rọ̀ kan, kò sí ẹ̀dá náà tí ó lè yà wá kúrò ninu ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa nípasẹ̀ Kristi Jesu Oluwa wa. Ọlọrun ṣe èyí kí á lè tẹ̀lé ìlànà Òfin ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àní àwa tí ìhùwàsí wa kì í ṣe bíi tí ẹni tí ẹran-ara ń lò ṣugbọn bí àwọn ẹni tí Ẹ̀mí ń darí. Nítorí àwọn tí ó ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ẹran- ara ń lò a máa lépa ìtẹ́lọ́rùn fún ẹran-ara; ṣugbọn àwọn tí Ẹ̀mí ń darí a máa lépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí. Lílépa àwọn nǹkan ti ẹran-ara nìkan a máa yọrí sí ikú, ṣugbọn lílépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí a máa fúnni ní ìyè ati alaafia. Ìdí nìyí tí àwọn tí ń lépa nǹkan ti ẹran-ara nìkan fi jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun, nítorí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè fara wọn sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun; wọn kò tilẹ̀ lè ṣe é rárá ni. Àwọn tí ń ṣe ìfẹ́ ẹran-ara wọn kò lè sin Ọlọrun. Ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí mọ́; Ẹ̀mí ló ń ṣamọ̀nà yín, bí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń gbé inú yín nítòótọ́. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ní Ẹ̀mí Kristi ninu rẹ̀, kì í ṣe ti Kristi. Ọlọrun Yan Israẹli. Òtítọ́ ni ohun tí mò ń sọ yìí; n kò purọ́, nítorí Kristi ni ó ni mí. Ọkàn mi tí Ẹ̀mí ń darí sì jẹ́ mi lẹ́rìí pẹlu, pé, Èyí nìkan kọ́. Rebeka bímọ meji fún ẹnìkan ṣoṣo, òun náà ni baba wa Isaaki. Ṣugbọn kí á tó bí àwọn ọmọ náà, àní sẹ́, kí wọ́n tó dá ohunkohun ṣe, yálà rere ni tabi burúkú, ni Ọlọrun ti sọ fún Rebeka pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo máa ṣe iranṣẹ àbúrò rẹ̀.” Báyìí ni Ọlọrun ti ń ṣe ìpinnu rẹ̀ láti ayébáyé, nígbà tí ó bá yan àwọn kan. Ó wá hàn kedere pé Ọlọrun kì í wo iṣẹ́ ọwọ́ eniyan kí ó tó yàn wọ́n; àwọn tí ó bá pinnu tẹ́lẹ̀ láti yàn ní í pè. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Jakọbu ni mo yàn, Esau ni mo kọ̀.” Kí ni kí á wá wí sí èyí? Kí á wí pé Ọlọrun ń ṣe àìdára ni bí? Rárá o! Nítorí ó sọ fún Mose pé, “Ẹni tí mo bá fẹ́ ṣàánú ni n óo ṣàánú; ẹni tí mo bá sì fẹ́ yọ́nú sí ni n óo yọ́nú sí.” Nítorí náà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí eniyan ti fẹ́ tabi bí ó ti gbìyànjú tó ni Ọlọrun fi ń yàn án, bí ó bá ti wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ ni. Nítorí Ọlọrun sọ ninu Ìwé Mímọ́ nípa Farao pé, “Ìdí tí mo fi fi ọ́ jọba ni pé, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe àpẹẹrẹ bí agbára mi ti tó, ati pé kì ìròyìn orúkọ mi lè tàn ká gbogbo ayé.” Nítorí náà, ẹni tí ó bá wu Ọlọrun láti ṣàánú, a ṣàánú rẹ̀, ẹni tí ó bá sì wù ú láti dí lọ́kàn, a dí i lọ́kàn. Wàyí, ẹnìkan lè sọ fún mi pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló dé tí Ọlọrun fi ń bá eniyan wí? Ta ni ó tó takò ó pé kí ó má ṣe ohun tí ó bá wù ú?” ohun ìbànújẹ́ ńlá ati ẹ̀dùn ọkàn ni ọ̀ràn àwọn eniyan mi jẹ́ fún mi nígbà gbogbo. Ṣugbọn ta ni ọ́, ìwọ ọmọ-eniyan, tí o fi ń gbó Ọlọrun lẹ́nu? Ǹjẹ́ ìkòkò lè wí fún ẹni tí ó ń mọ ọ́n pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe mí báyìí?” Àbí amọ̀kòkò kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe amọ̀ rẹ̀ bí ó ti wù ú bí? Bí ó bá fẹ́, ó lè fi amọ̀ rẹ̀ mọ ìkòkò tí ó wà fún èèlò ọ̀ṣọ́. Bí ó bá sì tún fẹ́, ó lè mú lára amọ̀ kan náà kí ó fi mọ ìkòkò mìíràn fún èèlò lásán. Bẹ́ẹ̀ náà ni ohun tí Ọlọrun ṣe rí. Ó wù ú láti fi ibinu ati agbára rẹ̀ hàn. Ó wá fi ọ̀pọ̀ sùúrù fara da àwọn tí ó yẹ kí ó fi ibinu parun. Báyìí náà ni ó fi ògo ńlá rẹ̀ hàn pẹlu fún àwọn tí ó ṣàánú fún, àní fún àwa tí ó ti pèsè ọlá sílẹ̀ fún. Àwa náà ni ó pè láti ààrin àwọn Juu ati láti ààrin àwọn tí kìí ṣe Juu pẹlu; bí ó ti sọ ninu Ìwé Hosia pé, “Èmi yóo pe àwọn tí kì í ṣe eniyan mi ní ‘Eniyan mi.’N óo sì pe àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò náání ní ‘Àyànfẹ́ mi.’ Ní ibìkan náà tí a ti sọ fún wọn rí pé, ‘Ẹ kì í ṣe eniyan mi mọ́’ni a óo ti pè wọ́n níọmọ Ọlọrun alààyè.” Aisaya náà kéde nípa Israẹli pé, “Bí àwọn ọmọ Israẹli tilẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn òkun, sibẹ díẹ̀ péré ni a óo gbà là. Nítorí ṣókí ati wéré wéré ni ìdájọ́ Ọlọrun yóo jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.” Ṣiwaju eléyìí, Aisaya sọ bákan náà pé, “Bíkòṣe pé Oluwa alágbára jùlọ dá díẹ̀ sí ninu àwọn ọmọ wa ni, bíi Sodomu ni à bá rí, à bá sì dàbí Gomora.” Mo fẹ́rẹ̀ lè gbadura pé kí á sọ èmi fúnra mi di ẹni ègún, kí á yà mí nípa kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí ti àwọn ará mi, àwọn tí a jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà. Kí ni èyí já sí? Ó já sí pé àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bìkítà rárá láti wá ojurere Ọlọrun, àwọn náà gan-an ni Ọlọrun wá dá láre, ó dá wọn láre nítorí wọ́n gbàgbọ́; ṣugbọn Israẹli tí ó ń lépa òfin tí yóo mú wọn rí ìdáláre gbà níwájú Ọlọrun kò rí irú òfin bẹ́ẹ̀. Nítorí kí ni wọn kò ṣe rí òfin náà? Ìdí ni pé, wọn kò wá ìdáláre níwájú Ọlọrun nípa igbagbọ, ṣugbọn wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọ́n bá kọsẹ̀ lórí òkúta ìkọsẹ̀, bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Mo gbé òkúta kan kalẹ̀ ní Sionití yóo mú eniyan kọsẹ̀,tí yóo gbé eniyan ṣubú.Ṣugbọn ojú kò ní ti ẹni tí ó bá gbà á gbọ́.” Ọmọ Israẹli ni wọ́n. Àwọn ni Ọlọrun yàn bí ọmọ rẹ̀. Àwọn ni ó fi ògo rẹ̀ hàn fún. Àwọn náà ni ó bá dá majẹmu, tí ó fún ní Òfin rẹ̀, tí ó sì kọ́ lọ́nà ẹ̀sìn rẹ̀. Àwọn ni ó ṣe ìlérí fún. Àwọn ni irú-ọmọ àwọn baba-ńlá ayé àtijọ́. Láàrin wọn ni Mesaya sì ti wá sáyé gẹ́gẹ́ bí eniyan. Ìyìn ni fún Ọlọrun, ẹni tíí ṣe olùdarí ohun gbogbo, lae ati laelae. Amin. Sibẹ, kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti kùnà patapata. Nítorí kì í ṣe gbogbo àwọn tí a bí sinu ìdílé Israẹli ni ọmọ Israẹli tòótọ́. Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ìran Abrahamu ni ọmọ rẹ̀ tòótọ́, nítorí bí Ìwé Mímọ́ ti wí, Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Àwọn ọmọ Isaaki nìkan ni a óo kà sí ìran fún ọ.” Èyí ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ tí a bí nípa ti ara lásán ni ọmọ Ọlọrun. Àwọn ọmọ tí a bí nípa ìlérí Ọlọrun ni a kà sí ìran Abrahamu. Nítorí báyìí ni ọ̀rọ̀ ìlérí náà: “Nígbà tí mo bá pada wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóo ti bí ọmọkunrin kan.” Elimeleki ati Ìdílé Rẹ̀ Lọ láti Máa Gbé ní Ilẹ̀ Moabu. Ní àkókò tí àwọn adájọ́ ń ṣe olórí ní ilẹ̀ Israẹli, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà. Ọkunrin kan wà, ará Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, òun ati aya rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeeji; wọ́n lọ ń gbé ilẹ̀ Moabu. Wọ́n dáhùn, wọ́n ní, “Rárá o, a óo bá ọ pada lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ.” Naomi dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi. Kí ló dé tí ẹ fẹ́ bá mi lọ? Ọmọ wo ló tún kù ní ara mi tí n óo ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí yóo ṣú yín lópó? Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ máa bá tiyín lọ. Ogbó ti dé sí mi, n kò tún lè ní ọkọ mọ́. Bí mo bá tilẹ̀ wí pé mo ní ìrètí, tí mo sì ní ọkọ ní alẹ́ òní, tí mo sì bí àwọn ọmọkunrin, ṣé ẹ óo dúró títí wọn óo fi dàgbà ni, àbí ẹ óo sọ pé ẹ kò ní ní ọkọ mọ́? Kò ṣeéṣe, ẹ̀yin ọmọ mi. Ó dùn mí fun yín pé OLUWA ti bá mi jà.” Wọ́n bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Nígbà tí ó yá, Opa fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì dágbére fún un; ṣugbọn Rutu kò kúrò lọ́dọ̀ ìyakọ rẹ̀. Naomi bá sọ fún Rutu, ó ní, “Ṣé o rí i pé arabinrin rẹ ti pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ati àwọn oriṣa rẹ̀, ìwọ náà pada, kí ẹ jọ máa lọ.” Ṣugbọn Rutu dáhùn, ó ní, “Má pàrọwà fún mi rárá, pé kí n fi ọ́ sílẹ̀, tabi pé kí n pada lẹ́yìn rẹ; nítorí pé ibi tí o bá ń lọ, ni èmi náà yóo lọ; ibi tí o bá ń gbé ni èmi náà yóo máa gbé; àwọn eniyan rẹ ni yóo máa jẹ́ eniyan mi, Ọlọrun rẹ ni yóo sì jẹ́ Ọlọrun mi. Ibi tí o bá kú sí, ni èmi náà yóo kú sí; níbẹ̀ ni wọn yóo sì sin mí sí pẹlu. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ yìí, kí OLUWA jẹ́ kí ohun tí ó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ bá mi, bí mo bá jẹ́ kí ohunkohun yà mí kúrò lẹ́yìn rẹ, ìbáà tilẹ̀ jẹ́ ikú.” Nígbà tí Naomi rí i pé Rutu ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀ láti bá òun lọ, kò sọ ohunkohun mọ́. Àwọn mejeeji bá bẹ̀rẹ̀ sí lọ títí wọ́n fi dé Bẹtilẹhẹmu. Nígbà tí wọ́n wọ Bẹtilẹhẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì nítorí wọn. Àwọn obinrin bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ṣé Naomi nìyí?” Orúkọ ọkunrin náà ni Elimeleki, aya rẹ̀ ń jẹ́ Naomi, àwọn ọmọkunrin rẹ̀ sì ń jẹ́ Maloni ati Kilioni. Wọ́n kó kúrò ní Efurata ti Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Moabu, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Naomi bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ má pè mí ní Naomi mọ́, Mara ni kí ẹ máa pè mí nítorí pé Olodumare ti jẹ́ kí ayé korò fún mi. Mo jáde lọ ní kíkún, ṣugbọn OLUWA ti mú mi pada ní ọwọ́ òfo, kí ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Naomi, nígbà tí OLUWA fúnra rẹ̀ ti dá mi lẹ́bi, tí Olodumare sì ti mú ìpọ́njú bá mi?” Báyìí ni Naomi ati Rutu, ará Moabu, aya ọmọ rẹ̀, ṣe pada dé láti ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Ní àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà baali ni wọ́n dé sí Bẹtilẹhẹmu. Nígbà tí ó yá, Elimeleki kú, ó bá ku Naomi, opó rẹ̀, ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ mejeeji. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ Moabu, Iyawo ẹnikinni ń jẹ́ Opa, ti ẹnìkejì sì ń jẹ́ Rutu. Lẹ́yìn nǹkan bíi ọdún mẹ́wàá tí wọ́n ti jọ ń gbé ilẹ̀ Moabu, Maloni ati Kilioni náà kú, Naomi sì ṣe bẹ́ẹ̀ ṣòfò àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji ati ọkọ rẹ̀. Naomi ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji jáde kúrò ní ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń pada lọ sí ilẹ̀ Juda, nítorí ó gbọ́ pé OLUWA ti ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda, ati pé wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ. Òun ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ bá gbéra láti ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ Juda. Bí wọ́n ti ń lọ, Naomi yíjú pada sí àwọn mejeeji, ó ní, “Ẹ̀yin mejeeji, ẹ pada sí ilé ìyá yín. Kí OLUWA ṣàánú fun yín, bí ẹ ti ṣàánú fún èmi ati àwọn òkú ọ̀run. Kí OLUWA ṣe ilé ọkọ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá tún ní, ní ilé rẹ̀.” Ó bá kí wọn, ó fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, ó dágbére fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Rutu Ṣiṣẹ́ ninu Oko Boasi. Ní àkókò yìí, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà ninu ìdílé Elimeleki, ẹbí kan náà ni ọkunrin yìí ati ọkọ Naomi. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi. Rutu bá wólẹ̀ ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Mo dúpẹ́ pé mo rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ tó báyìí, o sì ṣe akiyesi mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlejò ni mí.” Ṣugbọn Boasi dá a lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ìyá ọkọ rẹ, láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú ni wọ́n ti sọ fún mi patapata, ati bí o ti fi baba ati ìyá rẹ sílẹ̀, tí o kúrò ní ìlú yín, tí o wá sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan tí o kò mọ̀ rí. OLUWA yóo san ẹ̀san gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ọ. Abẹ́ ìyẹ́ apá OLUWA Ọlọrun Israẹli ni o wá, fún ààbò, yóo sì fún ọ ní èrè kíkún.” Rutu bá dáhùn, ó ní, “O ṣàánú mi gan-an ni, oluwa mi, nítorí pé o ti tù mí ninu, o sì ti fi sùúrù bá èmi iranṣẹbinrin rẹ sọ̀rọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin rẹ.” Nígbà tí àkókò oúnjẹ tó, Boasi pe Rutu, ó ní, “Wá jẹun, kí o fi òkèlè rẹ bọ inú ọtí kíkan.” Rutu bá jókòó lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń kórè ọkà, Boasi gbé ọkà yíyan nawọ́ sí i; ó sì jẹ àjẹyó ati àjẹṣẹ́kù. Nígbà tí Rutu dìde, láti tún máa ṣa ọkà, Boasi pàṣẹ fún àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí ó máa ṣa ọkà láàrin àwọn ìtí ọkà tí ẹ dì jọ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu. Kí ẹ tilẹ̀ fa ọkà yọ fún un ninu ìtí, kí ẹ sì tún fi í sílẹ̀ láti ṣa ọkà, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu.” Rutu bá tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣa ọkà. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ó pa ọkà tí ó ṣà, ohun tí ó rí tó ìwọ̀n efa ọkà baali kan. Ó gbé e, ó sì lọ sílé. Ó fi ọkà tí ó rí han ìyá ọkọ rẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ tí ó jẹ kù. Ìyá ọkọ rẹ̀ bi í léèrè, ó ní, “Níbo ni o ti ṣa ọkà lónìí, níbo ni o sì ti ṣiṣẹ́? OLUWA yóo bukun ẹni tí ó ṣàkíyèsí rẹ.”Rutu bá sọ inú oko ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀, ó ní, “Inú oko ọkunrin kan tí wọ́n ń pè ní Boasi ni mo ti ṣa ọkà lónìí.” Ní ọjọ́ kan, Rutu sọ fún Naomi, ó ní, “Jẹ́ kí n lọ sí oko ẹnìkan, tí OLUWA bá jẹ́ kí n bá ojurere rẹ̀ pàdé, n ó máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọ́n ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀.” Naomi bá dá a lóhùn, ó ní, “Ó dára, máa lọ, ọmọ mi.” Naomi dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA tí kì í gbàgbé láti ṣàánú ati òkú ọ̀run, ati alààyè bukun Boasi.” Naomi bá ṣe àlàyé fún Rutu pé, ẹbí àwọn ni Boasi, ati pé ọ̀kan ninu àwọn tí ó súnmọ́ wọn pẹ́kípẹ́kí ni. Rutu tún fi kún un fún Naomi pé, “Boasi tilẹ̀ tún wí fún mi pé, n kò gbọdọ̀ jìnnà sí àwọn iranṣẹ òun títí tí wọn yóo fi parí ìkórè ọkà Baali rẹ̀.” Naomi dáhùn, ó ní, “Ó dára, máa bá àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ, ọmọ mi, kí wọ́n má baà yọ ọ́ lẹ́nu bí o bá lọ sinu oko ọkà ẹlòmíràn.” Rutu bá ń bá àwọn ọmọbinrin Boasi lọ láti ṣa ọkà títí wọ́n fi parí ìkórè ọkà Baali, ó sì ń gbé ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀. Rutu bá gbéra, ó lọ sí oko ọkà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣa ọkà tí àwọn tí wọn ń kórè ọkà gbàgbé sílẹ̀. Oko tí ó lọ jẹ́ ti Boasi, ìbátan Elimeleki. Kò pẹ́ pupọ ni Boasi náà dé láti Bẹtilẹhẹmu. Ó kí àwọn tí wọn ń kórè ọkà, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín.” Àwọn náà dáhùn pé, “Kí OLUWA bukun ọ.” Boasi bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ó jẹ́ alákòóso àwọn tí ń kórè, ó ní, “Ọmọ ta ni ọmọbinrin yìí?” Iranṣẹ rẹ̀ náà bá dá a lóhùn, ó ní, “Obinrin ará Moabu, tí ó bá Naomi pada láti ilẹ̀ Moabu ni. Ó bẹ̀ wá pé kí á jọ̀wọ́ kí á fún òun ní ààyè láti máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọn ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀. Láti àárọ̀ tí ó ti dé, ni ó ti ń ṣiṣẹ́ títí di àkókò yìí láìsinmi, bí ó ti wù kí ó mọ.” Boasi bá pe Rutu, ó ní, “Gbọ́, ọmọ mi, má lọ sí oko ẹlòmíràn láti ṣa ọkà, má kúrò ní oko yìí, ṣugbọn faramọ́ àwọn ọmọbinrin mi. Oko tí wọn ń kórè rẹ̀ yìí ni kí o kọjú sí, kí o sì máa tẹ̀lé wọn. Mo ti kìlọ̀ fún àwọn ọdọmọkunrin wọnyi pé wọn kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu. Nígbà tí òùgnbẹ bá ń gbẹ ọ́, lọ sí ìdí àmù, kí o sì mu ninu omi tí àwọn ọdọmọkunrin wọnyi bá pọn.” Rutu rí Ọkọ Fẹ́. Lẹ́yìn náà, Naomi pe Rutu, ó ní, “Ọmọ mi, ó tó àkókò láti wá ọkọ fún ọ, kí ó lè dára fún ọ. Boasi bá dáhùn, ó ní, “OLUWA yóo bukun fún ọ, ọmọ mi, oore tí o ṣe ní ìkẹyìn yìí tóbi ju ti àkọ́kọ́ lọ; nítorí pé o kò wá àwọn ọdọmọkunrin lọ, kì báà jẹ́ olówó tabi talaka. Má bẹ̀rù, ọmọ mi, gbogbo ohun tí o bèèrè ni n óo ṣe fún ọ, nítorí pé gbogbo àwọn ọkunrin ẹlẹgbẹ́ mi ní ilẹ̀ yìí ni wọ́n mọ̀ pé obinrin gidi ni ọ́. Òtítọ́ ni mo jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ rẹ, ṣugbọn ẹnìkan wà tí ó tún súnmọ́ ọn jù mí lọ. Sùn títí di òwúrọ̀, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ bí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn láti ṣú ọ lópó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ rẹ̀, ó dára, jẹ́ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbátan, bí OLUWA ti wà láàyè, n óo ṣe ẹ̀tọ́, gẹ́gẹ́ bí ìbátan tí ó súnmọ́ ọn. Sùn títí di òwúrọ̀.” Rutu bá sùn lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, ṣugbọn ó tètè dìde ní àfẹ̀mọ́jú, kí eniyan tó lè dá eniyan mọ̀. Boasi bá kìlọ̀ fún un pé, “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ pé o wá sí ibi ìpakà.” Boasi sọ fún un pe kí ó tẹ́ aṣọ ìlékè rẹ̀, kí ó sì fi ọwọ́ mú un, Rutu náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Boasi wọn ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa sinu aṣọ náà, ó dì í, ó gbé e ru Rutu, Rutu sì pada sí ilé. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀, ìyá ọkọ rẹ̀ bi í pé, “Báwo ni ibẹ̀ ti rí, ọmọ mi?”Rutu bá sọ gbogbo ohun tí ọkunrin náà ṣe fún un. Ó ní, “Ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa ni ó dì fún mi, nítorí ó sọ pé n kò gbọdọ̀ pada sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ mi ní ọwọ́ òfo.” Naomi bá dáhùn, ó ní, “Fara balẹ̀ ọmọ mi, títí tí o óo fi gbọ́ bí ọ̀rọ̀ náà yóo ti yọrí sí; nítorí pé ara ọkunrin yìí kò ní balẹ̀ títí tí yóo fi yanjú ọ̀rọ̀ náà lónìí.” Ṣé o ranti pé ìbátan wa ni Boasi, tí o wà pẹlu àwọn ọmọbinrin rẹ̀? Wò ó, yóo lọ fẹ́ ọkà baali ní ibi ìpakà rẹ̀ lálẹ́ òní. Nítorí náà, lọ wẹ̀, kí o sì fi nǹkan pa ara. Wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ibi ìpakà rẹ̀, ṣugbọn má jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí ó bá jẹ tí ó sì mu tán. Nígbà tí ó bá fẹ́ sùn, ṣe akiyesi ibi tí ó sùn sí dáradára, lẹ́yìn náà, lọ ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì sùn tì í, lẹ́yìn náà, yóo sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ.” Rutu bá dá Naomi lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni n óo ṣe.” Rutu bá lọ sí ibi ìpakà, ó ṣe bí ìyá ọkọ rẹ̀ ti sọ fún un. Nígbà tí Boasi jẹ, tí ó mu tán, tí inú rẹ̀ sì dùn, ó lọ sùn lẹ́yìn òkítì ọkà Baali tí wọ́n ti pa. Rutu bá rọra lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sùn tì í. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, Boasi tají lójijì, bí ó ti yí ara pada, ó rí i pé obinrin kan sùn ní ibi ẹsẹ̀ òun. Ó bá bèèrè, pé, “Ìwọ ta ni?”Rutu dáhùn, ó ní, “Èmi Rutu, iranṣẹbinrin rẹ ni. Da aṣọ rẹ bo èmi iranṣẹbinrin rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ mi jùlọ.” Boasi Ṣú Rutu Lópó. Boasi bá lọ sí ẹnu ibodè ìlú, ó jókòó níbẹ̀. Bí ìbátan ọkọ Rutu tí ó súnmọ́ ọn, tí Boasi sọ nípa rẹ̀ ti ń kọjá lọ, ó pè é, ó ní, “Ọ̀rẹ́, yà sí ibí, kí o sì jókòó.” Ọkunrin náà bá yà, ó sì jókòó. Ati pé, mo ṣú Rutu, ará Moabu, opó Maloni lópó, ó sì di aya mi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ohun ìní rẹ̀, ati pé kí á má baà mú orúkọ rẹ̀ kúrò láàrin àwọn arakunrin rẹ̀ ati ní ẹnu ọ̀nà àtiwọ ìlú baba rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí.” Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ẹnu ọ̀nà ibodè ati àwọn àgbààgbà náà dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí, kí OLUWA kí ó ṣe obinrin tí ń bọ̀ wá di aya rẹ bíi Rakẹli ati Lea, tí wọ́n bí ọpọlọpọ ọmọ fún Jakọbu. Yóo dára fún ọ ní Efurata, o óo sì di olókìkí ní Bẹtilẹhẹmu. Àwọn ọmọ tí OLUWA yóo jẹ́ kí obinrin yìí bí fún ọ yóo kún ilé rẹ fọ́fọ́, bí ọmọ ti kún ilé Peresi, tí Tamari bí fún Juda.” Boasi bá ṣú Rutu lópó, Rutu sì di aya rẹ̀. Nígbà tí Boasi bá a lòpọ̀, ó lóyún, ó bí ọmọkunrin kan. Àwọn obinrin bá sọ fún Naomi pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, tí kò ṣe ọ́ ní aláìní ìbátan, kí OLUWA ṣe ọmọ náà ní olókìkí ní Israẹli. Ọmọ yìí yóo mú kí adùn ayé rẹ sọjí, yóo sì jẹ́ olùtọ́jú fún ọ ní ọjọ́ ogbó rẹ, nítorí iyawo ọmọ rẹ tí ó fẹ́ràn rẹ, tí ó sì ju ọmọkunrin meje lọ ni ó bímọ fún ọ.” Naomi bá gba ọmọ náà, ó tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì di olùtọ́jú rẹ̀. Àwọn obinrin àdúgbò bá sọ ọmọ náà ní Obedi, wọ́n ń sọ káàkiri pé, “A bí ọmọkunrin kan fún Naomi.” Obedi yìí ni baba Jese tíí ṣe baba Dafidi. Àwọn atọmọdọmọ Peresi nìwọ̀nyí: Peresi ni baba Hesironi; Hesironi bí Ramu, Ramu bí Aminadabu; Boasi pe àwọn mẹ́wàá ninu àwọn àgbààgbà ìlú, ó ní, “Ẹ wá jókòó sí ibí.” Wọ́n bá jókòó. Aminadabu bí Naṣoni; Naṣoni bí Salimoni; Salimoni bí Boasi, Boasi bí Obedi; Obedi bí Jese, Jese sì bí Dafidi. Lẹ́yìn náà, ó pe ìbátan ọkọ Rutu yìí, ó ní, “Naomi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ àwọn ará Moabu pada dé, fẹ́ ta ilẹ̀ kan tí ó jẹ́ ti Elimeleki ìbátan wa. Nítorí náà, mo rò ó ninu ara mi pé, kí n kọ́ sọ fún ọ pé kí o rà á, níwájú àwọn tí wọ́n jókòó níhìn-ín, ati níwájú àwọn àgbààgbà, àwọn eniyan wa; bí o bá gbà láti rà á pada, rà á. Ṣugbọn bí o kò bá fẹ́ rà á pada, sọ fún mi, kí n lè mọ̀, nítorí pé kò sí ẹni tí ó tún lè rà á pada, àfi ìwọ, èmi ni mo sì tẹ̀lé ọ.” Ọkunrin yìí dáhùn pé òun óo ra ilẹ̀ náà pada. Boasi bá fi kún un pé, “Ọjọ́ tí o bá ra ilẹ̀ yìí ní ọwọ́ Naomi, bí o bá ti ń ra ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni óo ra Rutu, ará ilẹ̀ Moabu, opó ọmọ Naomi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ogún rẹ̀.” Ìbátan Elimeleki yìí dáhùn, ó ní, “Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, n kò ní lè ra ilẹ̀ náà pada, nítorí kò ní jẹ́ kí àwọn ọmọ tèmi lè jogún mi bí ó ti yẹ. Bí o bá fẹ́, o lè fi ọwọ́ mú ohun tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ mi yìí, nítorí pé n kò lè rà á pada.” Ní àkókò yìí, ohun tí ó jẹ́ àṣà àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ètò ìràpada ati pàṣípààrọ̀ ohun ìní ni pé ẹni tí yóo bá ta nǹkan yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo sì kó o fún ẹni tí yóo rà á. Bàtà yìí ni ó dàbí ẹ̀rí ati èdìdì láàrin ẹni tí ń ta nǹkan ati ẹni tí ń rà á, ní ilẹ̀ Israẹli. Nítorí náà, nígbà tí ìbátan náà wí fún Boasi pé, “Rà á bí o bá fẹ́.” Ó bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ fún Boasi, Boasi bá sì sọ fún àwọn àgbààgbà ati gbogbo àwọn eniyan, ó ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí pé mo ti ra gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Elimeleki ati ti Kilioni ati ti Maloni lọ́wọ́ Naomi. Orin Kinni. Àwọn orin tí ó dùn jùlọ tí Solomoni kọ nìwọ̀nyí: Nǹkan ọ̀ṣọ́ mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́wà,ẹ̀gbà ọrùn sì mú kí ọrùn rẹ lẹ́wà. A óo ṣe àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà,tí a fi fadaka ṣe ọnà sí lára fún ọ. Nígbà tí ọba rọ̀gbọ̀kú lórí ìjókòó rẹ̀,turari mi ń tú òórùn dídùn jáde. Olùfẹ́ mi dàbí àpò òjíá,bí ó ti sùn lé mi láyà. Olùfẹ́ mi dàbí ìdì òdòdó igi Sipirẹsi,ninu ọgbà àjàrà Engedi. Wò ó! O mà dára o, olólùfẹ́ mi;o lẹ́wà pupọ.Ojú rẹ tutù bíi ti àdàbà. Háà, o mà dára o! Olùfẹ́ mi,o lẹ́wà gan-an ni.Ewéko tútù ni yóo jẹ́ ibùsùn wa. Igi Kedari ni òpó ilé wa,igi firi sì ni ọ̀pá àjà ilé wa. Wá fi ẹnu kò mí lẹ́nu,nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí waini lọ. Òróró ìpara rẹ ní òórùn dídùn,orúkọ rẹ dàbí òróró ìkunra tí a tú jáde;nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin ṣe fẹ́ràn rẹ. Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá,ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀.Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹa óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ;abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ! Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,mo dúdú lóòótọ́, ṣugbọn mo lẹ́wà,mo dàbí àgọ́ Kedari,mo rí bí aṣọ títa tí ó wà ní ààfin Solomoni. Má wò mí tìka-tẹ̀gbin, nítorí pé mo dúdú,oòrùn tó pa mí ló ṣe àwọ̀ mi bẹ́ẹ̀.Àwọn ọmọ ìyá mi lọkunrin bínú sí mi,wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà,ṣugbọn n kò tọ́jú ọgbà àjàrà tèmi alára. Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́:níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko?Níbo ni wọ́n ti ń sinmi,nígbà tí oòrùn bá mú?Kí n má baà máa wá ọ kiri,láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ? Ìwọ tí o lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn obinrin,bí o kò bá mọ ibẹ̀,ṣá máa tẹ̀lé ipa agbo ẹran.Jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹran rẹ máa jẹkolẹ́bàá àgọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan. Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé akọ ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun Farao. Ọkunrin. Òdòdó Ṣaroni ni mí,ati òdòdó Lílì tí ó wà ninu àfonífojì. Olùfẹ́ mi bá mi sọ̀rọ̀, ó wí fún mi pé,“Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi,jẹ́ kí á máa lọ.” Àkókò òtútù ti lọ,òjò sì ti dáwọ́ dúró. Àwọn òdòdó ti hù jáde,àkókò orin kíkọ ti tó,a sì ti ń gbọ́ ohùn àwọn àdàbà ní ilẹ̀ wa. Àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń so èso,àjàrà tí ń tanná,ìtànná wọn sì ń tú òórùn dídùn jáde.Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi,jẹ́ kí á máa lọ. Àdàbà mi, tí ó wà ninu pàlàpálá òkúta,ní ibi kọ́lọ́fín òkúta,jẹ́ kí n rójú rẹ, kí n gbọ́ ohùn rẹ,nítorí ohùn rẹ dùn, ojú rẹ sì dára. Mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ wọ̀n-ọn-nì,àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tí wọn ń ba ọgbà àjàrà jẹ́,nítorí ọgbà àjàrà wa tí ń tanná. Olùfẹ́ mi ni ó ni mí, èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi,ó ń da àwọn ẹran rẹ̀, wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì. Tún pada wá! Olùfẹ́ mi,títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,tí òjìji kò ní sí mọ́.Pada wá bí egbin ati akọ àgbọ̀nrín,lórí àwọn òkè págunpàgun. Bí òdòdó lílì ti rí láàrin ẹ̀gún,ni olólùfẹ́ mi rí láàrin àwọn ọmọge. Bí igi ápù ti rí láàrin àwọn igi igbó,ni olùfẹ́ mí rí láàrin àwọn ọmọkunrin.Pẹlu ìdùnnú ńlá ni mo fi jókòó lábẹ́ òjìji rẹ̀,èso rẹ̀ sì dùn lẹ́nu mi. Ó mú mi wá sí ilé àsè ńlá,ìfẹ́ ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi. Fún mi ni èso àjàrà gbígbẹ jẹ,kí ara mi mókun,fún mi ní èso ápù jẹ kí ara tù mí,nítorí pé, àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí. Ó wù mí kí ọwọ́ òsì rẹ̀ wà ní ìgbèrí mi,kí ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fà mí mọ́ra. Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,ní orúkọ egbin, ati ti àgbọ̀nrín pé,ẹ kò gbọdọ̀ jí ìfẹ́ títí yóo fi wù ú láti jí. Mo gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi, wò ó! Ó ń bọ̀,ó ń fò lórí àwọn òkè ńlá,ó sì ń bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké. Olólùfẹ́ mi dàbí egbin,tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín.Wò ó! Ó dúró lẹ́yìn ògiri ilé wa,ó ń yọjú lójú fèrèsé,ó ń yọjú níbi fèrèsé kékeré tí ó wà lókè. Orin Kẹta. Mo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́,lórí ibùsùn mi lálẹ́,mo wá a, ṣugbọn n kò rí i;mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn. Ó fi fadaka ṣe àwọn ẹsẹ̀ ìjókòó rẹ̀,ó fi wúrà ṣe ẹ̀yìn rẹ̀,Aṣọ elése-àlùkò tí àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu hun ni ó fi ṣe tìmùtìmù ìjókòó rẹ̀. Ẹ jáde lọ, ẹ̀yin ọmọbinrin Sioni,ẹ lọ wo Solomoni ọba,pẹlu adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e lórí,ní ọjọ́ igbeyawo,ní ọjọ́ ìdùnnú ati ọjọ́ ayọ̀ rẹ̀. N óo dìde nisinsinyii, n óo sì lọ káàkiri ìlú,n óo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́,ní gbogbo òpópónà ati ní gbogbo gbàgede.Mo wá a ṣugbọn n kò rí i. Àwọn aṣọ́de rí mi,bí wọ́n ṣe ń lọ káàkiri ìlú.Mo bèèrè lọ́wọ́ wọn pé,“Ǹjẹ́ ẹ rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?” Mo fẹ́rẹ̀ má tíì kúrò lọ́dọ̀ wọn,ni mo bá rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.Mo dì í mú, n kò sì jẹ́ kí ó lọ,títí tí mo fi mú un dé ilé ìyá mi,ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó lóyún mi. Mò ń kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,mo fi egbin ati àgbọ̀nrín inú igbó búra,pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi, títí yóo fi wù ú láti jí. Kí ló ń jáde bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí,tí ó dàbí òpó èéfín,tí ó kún fún òórùn dídùn òjíá ati turari,pẹlu òórùn dídùn àtíkè àwọn oníṣòwò? Wò ó! Solomoni ni wọ́n ń gbé bọ̀, lórí ìtẹ́ rẹ̀,ọgọta akọni ọkunrin, lára àwọn akọni Israẹli,ni ó yí ìtẹ́ rẹ̀ ká. Gbogbo wọn dira ogun pẹlu idà,akọni sì ni wọ́n lójú ogun.Olukuluku dira pẹlu idà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, nítorí ìdágìrì ọ̀gànjọ́. Igi Lẹbanoni ni Solomoni fi ṣe ìtẹ́ rẹ̀. Obinrin. Wò ó! O dára gan-an ni, olólùfẹ́ mi,ẹwà rẹ pọ̀.Ẹyinjú rẹ dàbí ti àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ,irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́,tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi. Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó! Arabinrin mi, iyawo mi,ìfẹ́ rẹ dùn ju waini lọ.Òróró ìkunra rẹ dára ju turari-kí-turari lọ. Oyin ní ń kán ní ètè rẹ, iyawo mi,wàrà ati oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ,òórùn dídùn aṣọ rẹ dàbí òórùn Lẹbanoni. Arabinrin mi dàbí ọgbà tí a ti ti ìlẹ̀kùn rẹ̀.Ọgbà tí a tì ni iyawo mi;àní orísun omi tí a tì ni ọ́. Àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ tí ń sọ dàbí ọgbà pomegiranate,tí ó kún fún èso tí ó dára jùlọ,àwọn bíi igi hena ati nadi; igi nadi ati Safironi, Kalamusi ati Sinamoni,pẹlu oríṣìíríṣìí igi turari,igi òjíá, ati ti aloe,ati àwọn ojúlówó turari tí òórùn wọn dára jùlọ. Ọgbà tí ó ní orísun omi ni ọ́,kànga omi tútù,àní, odò tí ń ṣàn, láti òkè Lẹbanoni. Dìde, ìwọ afẹ́fẹ́ ìhà àríwá,máa bọ̀, ìwọ afẹ́fẹ́ ìhà gúsù!Fẹ́ sórí ọgbà mi,kí òórùn dídùn rẹ̀ lè tàn káàkiri.Kí olùfẹ́ mi wá sinu ọgbà rẹ̀,kí ó sì jẹ èso tí ó bá dára jùlọ. Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn,tí wọn wá fọ̀;gbogbo wọn gún régé,Kò sí ọ̀kan kan tí ó yọ ninu wọn. Ètè rẹ dàbí òwú pupa;ẹnu rẹ fanimọ́ra,ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ ń dán bí ìlàjì èso Pomegiranate,lábẹ́ ìbòjú rẹ. Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi,tí a kọ́ fún ihamọra,ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ dàbí ẹgbẹrun (1000) asà tí a kó kọ́,bí apata àwọn akọni jagunjagun tí a kó jọ. Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji, tí wọn jẹ́ ìbejì,tí wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì. N óo wà lórí òkè òjíá,ati lórí òkè turari,títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,tí òkùnkùn yóo sì lọ. O dára gan-an ni, olùfẹ́ mi!O dára dára, o ò kù síbìkan,kò sí àbààwọ́n kankan lára rẹ. Máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni, iyawo mi,máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni.Kúrò ní ṣóńṣó òkè Amana,kúrò lórí òkè Seniri ati òkè Herimoni,kúrò ninu ihò kinniun, ati ibi tí àwọn ẹkùn ń gbé. O ti kó sí mi lẹ́mìí, arabinrin mi, iyawo mi,ẹ̀ẹ̀kan náà tí o ti ṣíjú wò mí,pẹlu nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn rẹ,ni o ti kó sí mi lórí. Obinrin. Mo wọ inú ọgbà mi,arabinrin mi, iyawo mi.Mo kó òjíá ati àwọn turari olóòórùn dídùn mi jọ,mo jẹ afárá oyin mi, pẹlu oyin inú rẹ̀,mo mu waini mi ati wàrà mi.Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ jẹ, kí ẹ sì mu,ẹ mu àmutẹ́rùn, ẹ̀yin olùfẹ́. Olùfẹ́ mi lẹ́wà pupọ, ó sì pupa,ó yàtọ̀ láàrin ẹgbaarun (10,000) ọkunrin. Orí rẹ̀ dàbí ojúlówó wúrà,irun rẹ̀ lọ́, ó ṣẹ́ léra wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ó dúdú bíi kóró iṣin. Ojú rẹ̀ dàbí àwọn àdàbà etí odò,tí a fi wàrà wẹ̀, tí wọ́n tò sí bèbè odò. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ dàbí ebè òdòdó olóòórùn dídùn,tí ń tú òórùn dídùn jáde.Ètè rẹ̀ dàbí òdòdó lílì,tí òróró òjíá ń kán níbẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ dàbí ọ̀pá wúrà,tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí lára.Ara rẹ̀ dàbí eyín erin tí ń dántí a fi òkúta safire bò. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí òpó alabasitatí a gbé ka orí ìtẹ́lẹ̀ wúrà.Ìrísí rẹ̀ dàbí òkè Lẹbanoni, ó rí gbọ̀ngbọ̀nràn bí igi Kedari. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn, àfi bí oyin,ó wuni lọpọlọpọ.Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,òun ni olùfẹ́ mi, òun sì ni ọ̀rẹ́ mi, Mo sùn ṣugbọn ọkàn mi kò sùn.Ẹ gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.Ṣílẹ̀kùn fún mi,arabinrin mi, olùfẹ́ mi,àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye,nítorí pé, ìrì ti mú kí orí mi tutù,gbogbo irun mi ti rẹ, fún ìrì alẹ́. Mo ti bọ́ra sílẹ̀,báwo ni mo ṣe lè tún múra?Mo ti fọ ẹsẹ̀ mi,báwo ni mo ṣe lè tún dọ̀tí rẹ̀? Olùfẹ́ mi gbọ́wọ́ lé ìlẹ̀kùn,ọkàn mi sì kún fún ayọ̀. Mo dìde, mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,gbogbo ọwọ́ mi kún fún òjíá,òróró òjíá sì ń kán ní ìka misára kọ́kọ́rọ́ ìlẹ̀kùn. Mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,ṣugbọn ó ti yipada, ó ti lọ.Mo fẹ́rẹ̀ dákú, nígbà tí ó sọ̀rọ̀,mo wá a, ṣugbọn n kò rí i,mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn. Àwọn aṣọ́de rí mibí wọ́n ti ń rìn káàkiri ìlú;wọ́n lù mí, wọ́n ṣe mí léṣe,wọ́n sì gba ìborùn mi. Mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,bí ẹ bá rí olùfẹ́ mi,ẹ bá mi sọ fún un pé:Àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí. Kí ni olùfẹ́ tìrẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ?Ìwọ arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin?Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ?Tí o fi ń kìlọ̀ fún wa bẹ́ẹ̀? Obinrin. Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,ìwọ, arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin?Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,kí á lè bá ọ wá a? Ta ni ń yọ bọ̀ bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ yìí,tí ó mọ́ bí ọjọ́,tí ó lẹ́wà bí òṣùpá.Tí ó sì bani lẹ́rù,bí àwọn ọmọ ogun tí wọn dira ogun? Mo lọ sinu ọgbà igi eléso,mo lọ wo ẹ̀ka igi tútù ní àfonífojì,pé bóyá àwọn àjàrà ti rúwé,ati pé bóyá àwọn igi èso pomegiranate tí ń tanná. Kí n tó fura,ìfẹ́ tí ṣe mí bí ẹni tí ó wà ninu ọkọ̀ ogun,tí ara ń wá bíi kí ó bọ́ sójú ogun. Máa pada bọ̀, máa pada bọ̀, ìwọ ọmọbinrin ará Ṣulamu.Máa pada bọ̀, kí á lè máa fi ọ́ ṣe ìran wò.Ẹ óo ṣe máa fi ará Ṣulamu ṣe ìran wòbí ẹni wo ẹni tí ó ń jóníwájú ọ̀wọ́ ọmọ ogun meji? Olùfẹ́ mi ti lọ sinu ọgbà rẹ̀,níbi ebè igi turari,ó da ẹran rẹ̀ lọ sinu ọgbà,ó lọ já òdòdó lílì. Olùfẹ́ mi ló ni mí,èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi.Láàrin òdòdó lílì,ni ó ti ń da ẹran rẹ̀. Olùfẹ́ mi, o dára bíi Tirisa.O lẹ́wà bíi Jerusalẹmu,O níyì bíi ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun tí ń gbé ọ̀págun. Yíjú kúrò lọ́dọ̀ mi,nítorí wọn kò jẹ́ kí n gbádùn.Irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́ ninu agbo,tí ń sọ̀kalẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi. Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan,tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ tán,gbogbo wọn gún régé,kò sì sí ọ̀kan tí ó yọ ninu wọn, Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ìlàjì èso pomegiranate lábẹ́ ìbòjú rẹ. Àwọn ayaba ìbáà tó ọgọta,kí àwọn obinrin mìíràn sì tó ọgọrin,kí àwọn iranṣẹbinrin sì pọ̀, kí wọn má lóǹkà, sibẹ, ọ̀kan ṣoṣo ni àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye.Ọmọlójú ìyá rẹ̀,ẹni tí kò ní àbààwọ́n lójú ẹni tí ó bí i.Àwọn iranṣẹbinrin ń pe ìyá rẹ̀ ní olóríire.Àwọn ayaba ati àwọn obinrin mìíràn ní ààfin sì ń yìn ín. Obinrin. Ẹsẹ̀ rẹ ti dára tó ninu bàtà,ìwọ, ọmọ aládé.Itan rẹ dàbí ohun ọ̀ṣọ́,tí ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà ṣe. Olùfẹ́ mi ló ni mí,èmi ni ọkàn rẹ̀ sì fẹ́. Máa bọ̀, olùfẹ́ mi,jẹ́ kí á jáde lọ sinu pápá,kí á lọ sùn ní ìletò kan. Kí á lọ sinu ọgbà àjàrà láàárọ̀ kutukutu,kí á wò ó bóyá àjàrà ti ń rúwé,bóyá ó ti ń tanná;kí á wò ó bóyá igi Pomegiranate ti ń tanná,níbẹ̀ ni n óo ti fi ìfẹ́ mi fún ọ. Èso Mandirake ń tú òórùn dídùn jáde,ẹnu ọ̀nà wa kún fún oríṣìíríṣìí èso tí ó wuni,tí mo ti pèsè wọn dè ọ́, olùfẹ́ mi,ati tuntun ati èyí tó ti pẹ́ nílé. Ìdodo rẹ dàbí abọ́,tí kì í gbẹ fún àdàlú waini,ikùn rẹ dàbí òkítì ọkà,tí a fi òdòdó lílì yíká. Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji,tí wọn jẹ́ ìbejì. Ọrùn rẹ dàbí ilé-ìṣọ́ tí wọn fi eyín erin kọ́.Ojú rẹ dàbí adágún omi ìlú Heṣiboni,tí ó wà ní ẹnubodè Batirabimu.Imú rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Lẹbanoni,tí ó dojú kọ ìlú Damasku. Orí rẹ dàbí adé lára rẹ, ó rí bí òkè Kamẹli,irun rẹ dàbí aṣọ elése-àlùkò tí ó ṣẹ́ léra, wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́irun orí rẹ ń dá ọba lọ́rùn. O dára, o wuni gan-an,olùfẹ́ mi, ẹlẹgẹ́ obinrin. Ìdúró rẹ dàbí igi ọ̀pẹ,ọyàn rẹ ṣù bí ìdì èso àjàrà. Mo ní n óo gun ọ̀pẹ ọ̀hún,kí n di odi rẹ̀ mú.Kí ọmú rẹ dàbí ìdì èso àjàrà,kí èémí ẹnu rẹ rí bí òórùn èso ápù. Ìfẹnukonu rẹ dàbí ọtí waini tí ó dára jùlọ,tí ń yọ́ lọ lọ́nà ọ̀fun,tí ń yọ́ lọ láàrin ètè ati eyín. Orin Kẹfa. Ìbá wù mí kí o jẹ́ ọmọ ìyá mi ọkunrin,kí ó jẹ́ pé ọmú kan náà ni a jọ mú dàgbà.Bí mo bá pàdé rẹ níta,tí mo fẹnu kò ọ́ lẹ́nu,kì bá tí sí ẹni tí yóo fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Ògiri ni mí,ọmú mi sì dàbí ilé-ìṣọ́;ní ojú olùfẹ́ mi,mo ní alaafia ati ìtẹ́lọ́rùn. Solomoni ní ọgbà àjàrà kan,ní Baali Hamoni.Ó fi ọgbà náà fún àwọn tí wọn yá a,ó ní kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú ẹgbẹrun (1,000) ìwọ̀n owó fadaka wá,fún èso ọgbà rẹ̀. Èmi ni mo ni ọgbà àjàrà tèmi,ìwọ Solomoni lè ní ẹgbẹrun ìwọ̀n owó fadaka,kí àwọn tí wọn yá ọgbà sì ní igba. Ìwọ tí ò ń gbé inú ọgbà,àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ń dẹtí,jẹ́ kí n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Yára wá, olùfẹ́ mi,yára bí egbin, tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín,sí orí àwọn òkè turari olóòórùn dídùn. Ǹ bá sìn ọ́ wá sílé ìyá mi,ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó tọ́ mi,ǹ bá fún ọ ní waini dídùn mu,àní omi èso Pomegiranate mi. Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní ìgbèrí mi,kí o sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ fà mí mọ́ra! Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin obinrin Jerusalẹmu,pé ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi,títí tí yóo fi wù ú láti jí. Ta ní ń bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí,tí ó fara ti olùfẹ́ rẹ̀?Lábẹ́ igi èso ápù ni mo ti jí ọ,níbi tí ìyá rẹ ti rọbí rẹ,níbi tí ẹni tí ó bí ọ ti rọbí. Gbé mi lé oókan àyà rẹ bí èdìdì ìfẹ́,bí èdìdì, ní apá rẹ;nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú.Owú jíjẹ burú, àfi bí isà òkú.A máa jó bí iná,bí ọwọ́ iná tí ó lágbára. Ọ̀pọ̀ omi kò lè pa iná ìfẹ́,ìgbì omi kò sì lè tẹ̀ ẹ́ rì.Bí eniyan bá gbìyànjú láti fi gbogbo nǹkan ìní rẹ̀ ra ìfẹ́,ẹ̀tẹ́ ni yóo fi gbà. A ní àbúrò obinrin kékeré kan,tí kò lọ́mú.Kí ni kí á ṣe fún arabinrin wa náàní ọjọ́ tí wọ́n bá wá tọrọ rẹ̀? Bí ó bá jẹ pé ògiri ni arabinrin wa,à óo mọ ilé-ìṣọ́ fadaka lé e lórí.Bí ó bá jẹ́ pé ìlẹ̀kùn ni,pákó Kedari ni a óo fi yí i ká. Ìkíni. Èmi Paulu, ẹrú Ọlọrun, ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí.Oluwa yàn mí láti jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ Ọlọrun lè ní igbagbọ ati ìmọ̀ òtítọ́ ti ẹ̀sìn, Nítorí àwọn alágídí pọ̀, tí wọn ń sọ̀rọ̀ asán, àwọn ẹlẹ́tàn, pàápàá jùlọ lára àwọn ọ̀kọlà. Dandan ni kí o pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí pé wọ́n ń da odidi agbo-ilé rú, wọ́n sì ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ tí kò tọ́ nítorí èrè tí kò yẹ. Ẹnìkan ninu wọn tí ó jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn wolii wọn sọ pé, “Òpùrọ́ paraku ni àwọn ará Kirete, ẹhànnà, ẹranko, ọ̀lẹ, alájẹkì.” Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí náà má gbojú fún wọn, bá wọn wí kí wọ́n lè ní igbagbọ tí ó pé. Kí wọn má máa lo àkókò wọn lórí ìtàn àròsọ àwọn Juu ati ìlànà àwọn eniyan tí wọ́n ti yapa kúrò lọ́nà òtítọ́. Gbogbo nǹkan ni ó mọ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ṣugbọn kò sí nǹkankan tí ó mọ́ fún àwọn alaigbagbọ tí èrò wọn ti wọ́, nítorí èrò wọn ati ẹ̀rí ọkàn wọn ti wọ́. Wọ́n ń fi ẹnu jẹ́wọ́ pé àwọn mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n ń sẹ́ ẹ ninu ìwà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹlẹ́gbin ati aláìgbọràn, wọn kò yẹ fún iṣẹ́ rere kan. ati ìrètí ìyè ainipẹkun, tí Ọlọrun tí kì í purọ́ ti ṣèlérí láti ayérayé. Ó ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn ní àkókò tí ó wọ̀ fún un ninu iwaasu tí ó ti fi lé mi lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Ọlọrun Olùgbàlà wa. Mò ń kọ ìwé yìí sí Titu, ọmọ mi tòótọ́ ninu ẹ̀sìn igbagbọ kan náà. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu Olùgbàlà wa, wà pẹlu rẹ̀. Ìdí tí mo ṣe fi ọ́ sílẹ̀ ní Kirete ni pé kí o ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó kù tí kò dára tó, kí o sì yan àwọn àgbà lórí ìjọ ní gbogbo ìlú, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlànà fún ọ. Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìlẹ́gàn, tí ó ní ẹyọ iyawo kan, tí àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ onigbagbọ, tí ẹnìkan kò lè fi ẹ̀sùn kàn pé ó ń hùwà wọ̀bìà tabi pé ó jẹ́ alágídí. Nítorí alabojuto ìjọ níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn gẹ́gẹ́ bí ìríjú Ọlọrun. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí yóo máa ṣe ti inú ara rẹ̀, tabi kí ó jẹ́ onínúfùfù. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà, tabi ẹni tí ó ní ìwọ̀ra nípa ọ̀rọ̀ owó. Ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn ati máa ṣe àlejò, tí ó sì fẹ́ ohun rere, ó yẹ kí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, olódodo, olùfọkànsìn, ẹni tí ó ń kó ara rẹ̀ níjàánu. Kí ó di ọ̀rọ̀ tòótọ́ tí a ti fi kọ́ ọ mú ṣinṣin, kí ó baà lè ní ọ̀rọ̀ ìwúrí nípa ẹ̀kọ́ tí ó yè, kí ó sì lè bá àwọn alátakò wí. Ẹ̀kọ́ tí ó Yè Kooro. Ní tìrẹ, àwọn ohun tí ó bá ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro mu ni kí ó máa ti ẹnu rẹ jáde. Kí wọn má máa ja ọ̀gá wọn lólè. Ṣugbọn kí wọn jẹ́ olóòótọ́ ati ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ní ọ̀nà gbogbo. Báyìí ni wọn yóo fi ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọrun Olùgbàlà wa lọ́ṣọ̀ọ́ ninu ohun gbogbo. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ti farahàn fún ìgbàlà gbogbo eniyan. Ó ń tọ́ wa sọ́nà pé kí á kọ ìwà aibikita fún Ọlọrun ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé sílẹ̀, kí á máa farabalẹ̀. Kí á máa gbé ìgbé-ayé òdodo, kí á sì jẹ́ olùfọkànsìn ní ayé yìí. Kí á máa dúró de ibukun tí à ń retí, ati ìfarahàn ògo Ọlọrun ẹni ńlá, ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa, láti rà wá pada kúrò ninu gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀, ati láti wẹ̀ wá mọ́ láti fi wá ṣe ẹni tirẹ̀ tí yóo máa làkàkà láti ṣe iṣẹ́ rere. Báyìí ni kí o máa wí fún wọn, kí o máa fi gbà wọ́n níyànjú kí o sì máa bá wọn wí nígbà gbogbo pẹlu àṣẹ. Má gbà fún ẹnikẹ́ni láti fojú tẹmbẹlu rẹ. Àwọn àgbà ọkunrin níláti jẹ́ ẹni tí ó ń ṣe pẹ̀lẹ́, ẹni ọ̀wọ̀, ọlọ́gbọ́n, tí ó jinná ninu igbagbọ, ninu ìfẹ́ ati ninu ìfaradà. Bákan náà, àwọn àgbà obinrin níláti jẹ́ ẹni tí gbogbo ìgbé-ayé wọn bá ti ìsìn Ọlọrun mu. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ onísọkúsọ tabi ẹrú ọtí. Wọ́n níláti máa kọ́ni ní ohun rere. Kí wọn máa fi òye kọ́ àwọn ọdọmọbinrin wọn láti fẹ́ràn ọkọ wọn ati ọmọ wọn. Kí wọn máa fara balẹ̀, kí wọn sì fara mọ́ ọkọ wọn nìkan. Kí wọn má ya ọ̀lẹ ninu iṣẹ́ ilé, kí wọn sì jẹ́ onínú rere. Kí wọn máa gbọ́ràn sí ọkọ wọn lẹ́nu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè sọ ìsọkúsọ sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Bákan náà, máa gba àwọn ọdọmọkunrin níyànjú láti fara balẹ̀. Kí o ṣe ara rẹ ní àpẹẹrẹ rere ní gbogbo ọ̀nà. Ninu ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́ àwọn eniyan, kí wọn rí òtítọ́ ninu rẹ, kí wọn sì rí ìwà àgbà lọ́wọ́ rẹ. Kí gbolohun ẹnu rẹ jẹ́ ti ọmọlúwàbí, tí ẹnìkan kò ní lè fi bá ọ wí. Èyí yóo mú ìtìjú bá ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe alátakò nígbà tí kò bá rí ohun burúkú kan sọ nípa wa. Kí àwọn ẹrú fi ara wọn sí abẹ́ àṣẹ ọ̀gá wọn ninu ohun gbogbo. Kí wọn máa ṣe nǹkan tí yóo tẹ́ wọn lọ́rùn, kí wọn má máa fún wọn lésì. Ìlànà nípa Ìwà Tí Ó Dára. Máa rán wọn létí kí wọn máa tẹríba fún ìjọba ati àwọn aláṣẹ, kí wọn máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, kí wọn sì múra láti máa ṣe iṣẹ́ rere gbogbo. Bí o bá ti kìlọ̀ fún adíjàsílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tabi lẹẹmeji, tí kò gbọ́, yẹra fún un. Mọ̀ pé ọkàn irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti wọ́, ó ń dá ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi. Nígbà tí mo bá rán Atemasi tabi Tukikọsi sí ọ, sa ipá rẹ láti wá sọ́dọ̀ mi ní ìlú Nikopoli, nítorí níbẹ̀ ni mo pinnu láti wà ní àkókò òtútù. Sa gbogbo ipá rẹ láti ran Senasi, lọ́yà, ati Apolo lọ́wọ́ kí wọn lè bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn, kí o sì rí i pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Àwọn eniyan wa níláti kọ́ láti ṣe iṣẹ́ rere kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà wọn; wọn kò gbọdọ̀ jókòó tẹtẹrẹ láìṣe nǹkankan. Gbogbo àwọn ẹni tí ó wà lọ́dọ̀ mi ní kí n kí ọ. Bá wa kí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa ninu igbagbọ.Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo yín. Kí wọn má sọ ìsọkúsọ sí ẹnikẹ́ni. Kí wọn kórìíra ìjà. Kí wọn ní ìfaradà. Kí wọ́n máa fi ìrẹ̀lẹ̀ bá gbogbo eniyan lò. Nítorí nígbà kan rí, àwa náà ń ṣe wérewère, à ń ṣe àìgbọràn, ayé ń tàn wá jẹ, a jẹ́ ẹrú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, a sì ń jẹ ayé ìjẹkújẹ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. À ń hùwà ìkà ati ìlara. A jẹ́ ohun ìríra fún àwọn eniyan. Àwa náà sì kórìíra ọmọnikeji wa. Ṣugbọn nígbà tí Ọlọrun fi inú rere ati ìfẹ́ rẹ̀ sí àwa eniyan hàn, ó gbà wá là; kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere kan tí a ṣe, ṣugbọn nítorí àánú rẹ̀ ni ó fi gbà wá là, nípa ìwẹ̀mọ́ pẹlu omi tí ó fi tún wa bí, ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fi sọ wá di ẹni titun. Ó da Ẹ̀mí yìí lé wa lórí lọpọlọpọ láti ọwọ́ Jesu Kristi Olùgbàlà wa. Ó dá wa láre nípa oore-ọ̀fẹ́ kan náà, tí a fi ní ìrètí láti di ajogún ìyè ainipẹkun. Ọ̀rọ̀ tí ó dájú ni ọ̀rọ̀ yìí.Mo fẹ́ kí o tẹnumọ́ àwọn nǹkan wọnyi, kí àwọn tí ó ti gba Ọlọrun gbọ́ lè fi ọkàn sí i láti máa ṣe iṣẹ́ tí ó dára. Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ dára, wọ́n sì ń ṣe eniyan ní anfaani. Ṣugbọn yẹra fún iyàn jíjà lórí ọ̀rọ̀ wèrè ati ìtàn ìrandíran, ati ìjà, ati àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ òfin. Nítorí wọn kò ṣe eniyan ní anfaani, wọn kò sì wúlò rárá. OLUWA Pe Àwọn Eniyan Rẹ̀ Pada Sọ́dọ̀. Ní oṣù kẹjọ, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA rán wolii Sakaraya, ọmọ Berekaya, ọmọ Ido, sí àwọn ọmọ Israẹli; ó ní, Ọkunrin tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni àwọn tí OLUWA rán láti máa rin ilẹ̀ ayé wò.” Wọ́n sì jíṣẹ́ fún angẹli OLUWA, tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà pé, “A ti lọ rin ilẹ̀ ayé wò jákèjádò, a sì rí i pé wọ́n wà ní alaafia ati ìdákẹ́rọ́rọ́.” Angẹli OLUWA bá dáhùn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, yóo ti pẹ́ tó kí o tó yọ́nú sí Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, tí o tí ń bínú sí láti aadọrin ọdún sẹ́yìn?” OLUWA sì dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn pẹlu ọ̀rọ̀ ìtùnú. Angẹli náà bá sọ fún mi pé kí n lọ kéde pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Mo ní ìfẹ́ ati ìtara tí ó jinlẹ̀ pupọ fún Jerusalẹmu ati Sioni. Inú sì ń bí mi gidigidi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí wọ́n sì wà ní alaafia; nítorí pé, nígbà tí mo bínú díẹ̀ sí àwọn eniyan mi, wọ́n tún dá kún ìṣòro wọn ni. Nítorí náà, mo ti pada sí Jerusalẹmu láti ṣàánú fún un: a óo tún ilé mi kọ́ sibẹ, a óo sì tún ìlú Jerusalẹmu kọ́.” Angẹli náà tún sọ fún mi pé, “Lọ kéde pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, àwọn ìlú òun yóo tún kún fún ọrọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, òun OLUWA yóo tu Sioni ninu, òun óo sì tún yan Jerusalẹmu ní àyànfẹ́ òun.” Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí ìwo mààlúù mẹrin, mo sì bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀.Ó bá dá mi lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn alágbára ayé tí wọ́n fọ́n Juda, Israẹli, ati Jerusalẹmu ká.” “Èmi OLUWA bínú sí àwọn baba ńlá yín. Nítorí náà, Lẹ́yìn náà, OLUWA fi àwọn alágbẹ̀dẹ mẹrin kan hàn mí. Mo bèèrè pé, “Kí ni àwọn wọnyi ń bọ̀ wá ṣe?”Ó bá dáhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn tí wọ́n fọ́n Juda ká patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ku ẹnìkan mọ́. Ṣugbọn àwọn alágbẹ̀dẹ wọnyi wá láti dẹ́rùba àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n fọ́n Juda ká, ati láti fọ́n àwọn náà ká.” èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ní kí ẹ pada wá sọ́dọ̀ mi, èmi náà yóo sì pada sọ́dọ̀ yín. Ẹ má ṣe bí àwọn baba ńlá yín, tí àwọn wolii mi rọ̀ títí pé kí wọ́n jáwọ́ ninu ìgbé-ayé burúkú, kí wọ́n jáwọ́ ninu iṣẹ́ ibi, ṣugbọn tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́. Níbo ni àwọn baba ńlá yín ati àwọn wolii wà nisinsinyii? Ǹjẹ́ wọ́n wà mọ́? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi ati ìlànà mi tí àwọn wolii, iranṣẹ mi, sọ kò ṣẹ sí àwọn baba ńlá yín lára?” Àwọn eniyan náà bá ronupiwada, wọ́n ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ṣe wá bí ó ti pinnu láti ṣe, nítorí ìwà burúkú ati iṣẹ́ ibi wa.” Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kọkanla tíí ṣe oṣù Ṣebati, ní ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA fi ìran kan han wolii Sakaraya ọmọ Berekaya, ọmọ Ido. Mo rí ìran kan lóru. Ninu ìran náà, mo rí ọkunrin kan lórí ẹṣin pupa, láàrin àwọn igi kan tí wọ́n ń pè ní mitili, láàrin àfonífojì kan. Àwọn ẹṣin pupa, ati ẹṣin rẹ́súrẹ́sú ati ẹṣin funfun dúró lẹ́yìn rẹ̀. Mo bá bèèrè pé, “OLUWA mi, kí ni ìtumọ̀ kinní wọnyi?” Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì dáhùn pé, “N óo sọ ìtumọ̀ wọn fún ọ.” OLUWA Ṣèlérí láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là. Ẹ bèèrè òjò lọ́wọ́ OLUWA ní àkókò rẹ̀, àní lọ́wọ́ OLUWA tí ó dá ìṣúdẹ̀dẹ̀ òjò; Òun ló ń fún eniyan ní ọ̀wààrà òjò, tí àwọn ohun ọ̀gbìn fi ń tutù yọ̀yọ̀. N óo kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn láti ilẹ̀ Ijipti wá,n óo kó wọn jọ láti ilẹ̀ Asiria;n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi ati ilẹ̀ Lẹbanoni,wọn óo kún ilẹ̀ náà tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ààyè mọ́. Wọn óo la òkun Ijipti kọjá,ìgbì rẹ̀ yóo sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.Odò Naili yóo gbẹ kanlẹ̀,a óo rẹ ìgbéraga ilẹ̀ Asiria sílẹ̀,agbára óo sì kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti. N óo sọ wọ́n di alágbára ninu èmi OLUWA,wọn yóo sì máa ṣògo ninu orúkọ mi.” Ìsọkúsọ ni àwọn ère ń sọ, àwọn aríran ń ríran èké; àwọn tí ń lá àlá ń rọ́ àlá irọ́, wọ́n sì ń tu àwọn eniyan ninu lórí òfo. Nítorí náà ni àwọn eniyan fi ń rìn káàkiri bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA ní, “Inú mi ru sí àwọn olùṣọ́-aguntan, n óo sì fìyà jẹ àwọn alákòóso. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń tọ́jú agbo mi, àní àwọn eniyan Juda, wọn yóo sì dàbí ẹṣin alágbára lójú ogun. Ninu wọn ni a óo ti rí òkúta igun ilé, tí a lè pè ní olórí, aṣaaju, ati aláṣẹ, láti ṣe àkóso àwọn eniyan mi. Gbogbo wọn óo jẹ́ akikanju lójú ogun, wọn óo tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro; wọn óo jagun, nítorí OLUWA wà pẹlu wọn, wọn óo sì dá àyà já àwọn tí wọn ń gun ẹṣin. “N óo sọ ilé Juda di alágbára,n óo sì gba ilé Josẹfu là.N óo mú wọn pada,nítorí àánú wọn ń ṣe mí,wọn yóo dàbí ẹni pé n kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ rí;nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn,n óo sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ wọn. Nígbà tó bá yá, ilé Efuraimu yóo dàbí jagunjagun alágbára,inú wọn yóo sì dùnbí inú ẹni tí ó mu ọtí waini.Nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá rí i,inú wọn yóo dùn,ọkàn wọn yóo sì yin OLUWA. “N óo ṣẹ́wọ́ sí wọn,n óo sì kó wọn jọ sinu ilé.Mo ti rà wọ́n pada,nítorí náà wọn yóo tún pọ̀ bíi ti àtẹ̀yìnwá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn kásí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè,sibẹsibẹ, wọn yóo ranti mi lọ́nà jíjìn tí wọ́n wà.Àwọn ati àwọn ọmọ wọn yóo wà láàyè,wọn yóo sì pada wá sí ilẹ̀ wọn. Ìṣubú Àwọn Aninilára. Ṣílẹ̀kùn rẹ, ìwọ ilẹ̀ Lẹbanonikí iná lè jó àwọn igi kedari rẹ! Mo bá mú ọ̀pá mi tí ń jẹ́ “Oore-ọ̀fẹ́,” mo dá a, mo fi fi òpin sí majẹmu tí mo bá àwọn orílẹ̀-èdè dá. Nítorí náà, majẹmu mi ti dópin lọ́jọ́ náà. Àwọn tí wọn ń ṣòwò aguntan, tí wọn ń wò mí, mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo ṣe ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú yín, ẹ fún mi ní owó iṣẹ́ mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ máa mú un lọ.” Wọ́n bá wọn ọgbọ̀n owó fadaka fún mi gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ mi. Nígbà náà ni OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ pa owó náà mọ́ sílé ìṣúra.” Nítorí náà, mo da ọgbọ̀n owó fadaka tí wọ́n san fún mi, sinu ilé ìṣúra ní ilé OLUWA. Nígbà náà ni mo dá ọ̀pá mi keji tí ń jẹ́ “Ìṣọ̀kan,” mo fi fi òpin sí àjọṣe tí ó wà láàrin Juda ati Israẹli. OLUWA tún sọ fún mi pé “Tún fi ara rẹ sí ipò darandaran tí kò wúlò fún nǹkankan. Wò ó! N óo gbé darandaran kan dìde tí kò ní bìkítà fún àwọn ẹran tí wọ́n ń ṣègbé, kò ní tọpa àwọn tí wọn ń ṣáko lọ, tabi kí ó wo àwọn tí ń ṣàìsàn sàn, tabi kí ó fún àwọn tí ara wọn le ní oúnjẹ. Dípò kí ó tọ́jú wọn, pípa ni yóo máa pa àwọn tí ó sanra jẹ, tí yóo sì máa fa pátákò wọn ya. Olùṣọ́-aguntan mi tí kò bá níláárí gbé! Tí ó ń fi agbo ẹran sílẹ̀. Idà ni yóo ṣá a ní apá, yóo sì bá a ní ojú ọ̀tún, apá rẹ̀ óo rọ patapata, ojú ọ̀tún rẹ̀ óo sì fọ́ patapata.” Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi Sipirẹsi,nítorí igi kedari ti ṣubú,àwọn igi ológo ti parun.Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi oaku ní Baṣani,nítorí pé, a ti gé àwọn igi igbó dídí Baṣani lulẹ̀! Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ gbọ́ ẹkún àwọn darandaran,nítorí ògo wọn ti díbàjẹ́.Ẹ gbọ́ bí àwọn kinniun ti ń bú ramúramù,nítorí igbó tí wọn ń gbélẹ́bàá odò Jọdani ti parun! Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ọlọrun mi sọ; ó ní, “Fi ara rẹ sí ipò olùṣọ́-aguntan tí ó da àwọn ẹran rẹ̀ lọ sí ibi tí wọ́n ti pa wọ́n. Àwọn tí wọ́n rà wọ́n pa wọ́n ní àpagbé; àwọn tí wọn n tà wọ́n sì wí pé, ‘Ìyìn ni fún OLUWA, mo ti di ọlọ́rọ̀’; àwọn tí wọ́n ni wọ́n kò tilẹ̀ ṣàánú wọn.” OLUWA ní, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni n kò ní ṣàánú àwọn eniyan ilẹ̀ yìí mọ́. Fúnra mi ni n óo fi wọ́n lé àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba wọn lọ́wọ́. Wọn óo run ilẹ̀ náà, n kò sì ní gba ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ wọn.” Mo ti di darandaran agbo ẹran tí à ń dà lọ fún àwọn alápatà. Mo mú ọ̀pá meji, mo sọ ọ̀kan ní “Oore-ọ̀fẹ́,” mo sì sọ ekeji ní “Ìṣọ̀kan.” Inú mi ru sí mẹta ninu àwọn darandaran tí wọ́n kórìíra mi, mo sì mú wọn kúrò láàrin oṣù kan. Mo wá sọ fún àwọn agbo ẹran náà pé, “N kò ní ṣe olùṣọ́ yín mọ́. Èyí tí yóo bá kú ninu yín kí ó kú, èyí tí yóo bá ṣègbé, kí ó ṣègbé, kí àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù sì máa pa ara wọn jẹ.” Ìlérí ìdáǹdè fún Jerusalẹmu. Iṣẹ́ tí OLUWA rán sí Israẹli nìyí, OLUWA tí ó ta ọ̀run bí aṣọ, tí ó dá ayé, tí ó sì dá ẹ̀mí sinu eniyan, ni ó sọ báyìí pé, “N óo fi ẹ̀mí àánú ati adura sí ọkàn àwọn ọmọ Dafidi ati àwọn ará Jerusalẹmu, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ pé, bí wọ́n bá wo ẹni tí wọ́n gún lọ́kọ̀, wọn yóo máa ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo. Wọn yóo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn bí ẹni tí àkọ́bí rẹ̀ ṣàìsí. Ní àkókò náà, ọ̀fọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu yóo pọ̀ bí ọ̀fọ̀ tí wọ́n ṣe fún Hadadi Rimoni ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Megido. Ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ilẹ̀ náà yóo ṣọ̀fọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dafidi yóo dá ọ̀fọ̀ tirẹ̀ ṣe, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iyawo wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Natani náà yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn iyawo wọn, àwọn náà óo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Lefi yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iyawo wọn, àwọn náà óo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Ṣimei pàápàá yóo ṣọ̀fọ̀ tirẹ̀ lọ́tọ̀, àwọn iyawo wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn náà lọ́tọ̀; gbogbo àwọn ìdílé yòókù ni wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn náà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn iyawo wọn náà yóo sì ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀.” “N óo ṣe ìlú Jerusalẹmu bí ife ọtí àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Wọn óo dojú kọ ilẹ̀ Juda, wọn óo sì dóti ìlú Jerusalẹmu. Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, n óo mú kí ilẹ̀ Jerusalẹmu le kankan bí òkúta tí ó wúwo, orílẹ̀-èdè tí ó bá dábàá pé òun óo ṣí i nídìí, yóo farapa yánnayànna. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo sì parapọ̀ láti bá a jà. Ní ọjọ́ náà, n óo dẹ́rùba àwọn ẹṣin, n óo sì fi wèrè kọlu àwọn tí wọn ń gùn wọ́n. Ṣugbọn n óo máa ṣọ́ àwọn ará Juda, n óo sì fọ́ ojú ẹṣin àwọn ọ̀tá wọn. Àwọn ará Juda yóo wá máa sọ láàrin ara wọn pé, ‘OLUWA, àwọn ọmọ ogun ti sọ àwọn ará Jerusalẹmu di alágbára.’ “Ní ọjọ́ náà, n óo jẹ́ kí àwọn ará Juda dàbí ìkòkò iná tí ń jó ninu igbó, àní, bí iná tí ń jó láàrin oko ọkà, wọn yóo jó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri, ṣugbọn Jerusalẹmu yóo wà láàyè rẹ̀ pẹlu gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. “OLUWA yóo kọ́kọ́ fún àwọn ogun Juda ní ìṣẹ́gun, kí ògo ilé Dafidi ati ògo àwọn ará Jerusalẹmu má baà ju ti Juda lọ. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo dáàbò bo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ẹni tí ó ṣe aláìlera jùlọ ninu wọn yóo lágbára bíi Dafidi. Ìdílé Dafidi yóo dàbí Ọlọrun, yóo máa darí wọn bí angẹli OLUWA. Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Àṣẹ pé kí Wọ́n Pa Àwọn Olùṣọ́-Aguntan Ọlọrun. OLUWA ní, “Nígbà tó bá yá, orísun omi kan yóo ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi, ati fún àwọn ará Jerusalẹmu láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà èérí wọn. “N óo gbá àwọn oriṣa kúrò ní ilẹ̀ náà débi pé ẹnikẹ́ni kò ní ranti wọn mọ́; bákan náà ni n óo mú gbogbo àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní wolii kúrò, ati àwọn ẹ̀mí àìmọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá pe ara rẹ̀ ní wolii, baba ati ìyá rẹ̀ tí ó bí i yóo wí fún un pé yóo kú, nítorí ó ń purọ́ ní orúkọ OLUWA. Bí ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀, baba ati ìyá rẹ̀ yóo gún un pa. Nígbà tí àkókò bá tó, ojú yóo ti olukuluku wolii fún ìran tí ó rí nígbà tí ó bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, kò sì ní wọ aṣọ onírun mọ́ láti fi tan eniyan jẹ. Ṣugbọn yóo sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe wolii, àgbẹ̀ ni mí; oko ni mò ń ro láti ìgbà èwe mi.’ Bí ẹnikẹ́ni bá bi í pé, ‘Àwọn ọgbẹ́ wo wá ni ti ẹ̀yìn rẹ?’ Yóo dáhùn pé, ‘Ọgbẹ́ tí mo gbà nílé àwọn ọ̀rẹ́ mi ni.’ ” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ìwọ idà, kọjú ìjà sí olùṣọ́ àwọn aguntan mi, ati sí ẹni tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Kọlu olùṣọ́-aguntan, kí àwọn aguntan lè fọ́nká; n óo kọjú ìjà sí àwọn aguntan kéékèèké. Jákèjádò ilẹ̀ náà, ìdá meji ninu mẹta àwọn eniyan náà ni wọn yóo kú, a óo sì dá ìdá kan yòókù sí. N óo da ìdá kan yòókù yìí sinu iná, n óo fọ̀ wọ́n mọ́, bí a tíí fi iná fọ fadaka. N óo sì dán wọn wò, bí a tíí dán wúrà wò. Wọn yóo pe orúkọ mi, n óo sì dá wọn lóhùn. N óo wí pé, ‘Eniyan mi ni wọ́n’; àwọn náà yóo sì jẹ́wọ́ pé, ‘OLUWA ni Ọlọrun wa.’ ” Jerusalẹmu ati Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Wò ó! Ọjọ́ OLUWA ń bọ̀ tí wọn yóo pín àwọn ìkógun tí wọ́n kó ní ilẹ̀ Jerusalẹmu lójú yín. A óo sọ gbogbo ilẹ̀ náà di pẹ̀tẹ́lẹ̀, láti Geba ní ìhà àríwá, títí dé Rimoni ní ìhà gúsù. Ṣugbọn Jerusalẹmu yóo yọ kedere láàrin àwọn ilẹ̀ tí ó yí i ká, láti ẹnubodè Bẹnjamini, lọ dé ẹnubodè àtijọ́ ati dé ẹnubodè Igun, láti ilé-ìṣọ́ Hananeli dé ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí fún ọba. Àwọn eniyan yóo máa gbé inú ìlú Jerusalẹmu, kò ní sí ègún mọ́, ìlú Jerusalẹmu yóo sì wà ní alaafia. Àjàkálẹ̀ àrùn tí OLUWA yóo fi bá àwọn tí wọ́n bá gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu jà nìyí: Ẹran ara wọn yóo rà nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè, ojú wọn yóo rà ninu ihò rẹ̀, ahọ́n wọn yóo sì rà lẹ́nu wọn. Tó bá di ìgbà náà, OLUWA yóo mú ìbẹ̀rùbojo bá wọn tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo fi máa pa ara wọn; Àwọn ará Juda pàápàá yóo máa bá àwọn ará Jerusalẹmu jà. A óo kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i ká jọ: ati fadaka, ati wúrà, ati ọpọlọpọ aṣọ. Àjàkálẹ̀ àrùn burúkú náà yóo kọlu àwọn ẹṣin, ìbakasíẹ, ràkúnmí, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá wà ní ibùdó ogun wọn. Àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù láti àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu yóo máa wá lọdọọdun láti sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ní ìlú Jerusalẹmu ati láti ṣe Àjọ̀dún Àgọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò lọ sí ìlú Jerusalẹmu lọ sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, òjò kò ní rọ̀ sí ilẹ̀ rẹ̀. Bí ó bá ṣe pé àwọn ará Ijipti ni wọ́n kọ̀ tí wọn kò wá síbi Àjọ̀dún Àgọ́ náà, irú àrùn tí OLUWA fi bá àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò wá sí ibi Àjọ Àgọ́ jà, ni yóo dà lé wọn lórí. Èyí ni ìyà tí yóo jẹ ilẹ̀ Ijipti ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò bá wá síbi Àjọ Àgọ́. Nítorí n óo kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ láti gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Wọn yóo ṣẹgun rẹ̀, wọn yóo kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rù lọ, wọn yóo sì fi tipátipá bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀. Ìdajì àwọn ará ìlú náà yóo lọ sóko ẹrú, ṣugbọn ìdajì yòókù ninu wọn yóo wà láàrin ìlú. Tó bá di ìgbà náà, a óo máa kọ “MÍMỌ́ SÍ OLUWA,” sí ara aago tí wọn ń so mọ́ ẹṣin lára. Ìkòkò inú ilé OLUWA, yóo sì máa dàbí àwọn àwo tí ó wà níwájú pẹpẹ. Gbogbo ìkòkò tí ó wà ní Jerusalẹmu ati ní Juda yóo di mímọ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun. Àwọn tí wọ́n wá ṣe ìrúbọ yóo máa se ẹran ẹbọ wọn ninu ìkòkò wọnyi. Kò ní sí oníṣòwò ní ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ tó bá di ìgbà náà. OLUWA yóo wá jáde, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jà, bí ìgbà tí ó ń jà lójú ogun. Tó bá di àkókò náà, yóo dúró lórí òkè olifi tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu; òkè olifi yóo sì pín sí meji. Àfonífojì tí ó gbòòrò yóo sì wà láàrin rẹ̀ láti apá ìlà oòrùn dé apá ìwọ̀ oòrùn. Apá kan òkè náà yóo lọ ìhà àríwá, apá keji yóo sì lọ sí ìhà gúsù. Ẹ óo sá àsálà gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó pín òkè náà sí meji. Ẹ óo sá bí àwọn baba ńlá yín ti sá nígbà tí ilẹ̀ mì tìtì ní àkókò Usaya, ọba Juda, OLUWA, Ọlọrun yín yóo wá dé, pẹlu gbogbo àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀. Tó bá di ìgbà náà, kò ní sí òtútù tabi òjò dídì mọ́, kò ní sí òkùnkùn, kò ní sí ọ̀sán, kò ní sí òru bíkòṣe ìmọ́lẹ̀ nígbà gbogbo. Ṣugbọn OLUWA nìkan ló mọ ìgbà tí nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀. Tó bá di ìgbà náà, àwọn odò tí wọ́n kún fún omi ìyè yóo máa ṣàn jáde láti Jerusalẹmu. Apá kan wọn yóo máa ṣàn lọ sinu òkun tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, apá keji yóo máa ṣàn lọ sí òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì máa rí bẹ́ẹ̀ tòjò-tẹ̀ẹ̀rùn. OLUWA yóo wá jọba ní gbogbo ayé; Ọlọrun nìkan ni gbogbo aráyé yóo máa sìn nígbà náà, orúkọ kanṣoṣo ni wọn yóo sì mọ̀ ọ́n. Ìran nípa Okùn Ìwọ̀n. Bí mo tún ti gbé ojú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó mú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́. OLUWA ní, “Ẹ kọrin ayọ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí inú yín máa dùn, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, nítorí pé mò ń bọ̀ wá máa ba yín gbé. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni yóo parapọ̀ láti di eniyan mi nígbà náà. N óo máa gbé ààrin yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo ranṣẹ si yín. N óo jogún Juda bí ohun ìní mi ninu ilẹ̀ mímọ́, n óo sì yan Jerusalẹmu.” Ẹ̀yin eniyan, ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA, nítorí ó ń jáde bọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀. Mo bi í pé, “Níbo ni ò ń lọ?” Ó bá dáhùn pé, “Mò ń lọ wọn Jerusalẹmu, kí n lè mọ òòró ati ìbú rẹ̀ ni.” Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá bọ́ siwaju, angẹli mìíràn sì lọ pàdé rẹ̀, Angẹli àkọ́kọ́ sọ fún ekeji pé, “Sáré lọ sọ fún ọmọkunrin tí ó ní okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ pé, eniyan ati ẹran ọ̀sìn yóo pọ̀ ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè mọ odi yí i ká. Èmi fúnra mi ni n óo jẹ́ odi iná tí n óo yí i ká, tí n óo máa dáàbò bò ó, n óo sì fi ògo mi kún inú rẹ̀.” OLUWA sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ àríwá. Lóòótọ́ èmi ni mo fọn yín ká bí afẹ́fẹ́ sí igun mẹrẹẹrin ayé, ṣugbọn nisinsinyii, ẹ sá àsálà lọ sí Sioni, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Babiloni. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó rán ni sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ko yín lẹ́rú, nítorí ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín, fọwọ́ kan ẹyinjú èmi OLUWA.” N óo bá àwọn ọ̀tá yín jà; wọn yóo sì di ẹrú àwọn tí ń sìn wọ́n.Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA àwọn ọmọ ogun. Ìran wolii náà nípa Olórí Alufaa. Lẹ́yìn náà, OLUWA fi Joṣua olórí alufaa hàn mí; ó dúró níwájú angẹli OLUWA, Satani sì dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti fi ẹ̀sùn kàn án. Ní ọjọ́ náà, olukuluku yóo pe aládùúgbò rẹ̀ láti wá bá a ṣe fàájì lábẹ́ àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀.” Angẹli OLUWA sọ fún Satani pé, “OLUWA óo bá ọ wí, ìwọ Satani! OLUWA tí ó yan Jerusalẹmu óo bá ọ wí! Ṣebí ẹ̀ka igi tí a yọ jáde láti inú iná ni ọkunrin yìí?” Joṣua dúró níwájú angẹli Ọlọrun, pẹlu aṣọ tí ó dọ̀tí ní ọrùn rẹ̀. Angẹli náà bá sọ fún àwọn tí wọ́n dúró tì í pé, “Ẹ bọ́ aṣọ tí ó dọ̀tí yìí kúrò lọ́rùn rẹ̀.” Ó bá sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò, n óo sì fi aṣọ tí ó lẹ́wà wọ̀ ọ́.” Ó bá pàṣẹ pé, “Ẹ fi aṣọ mímọ́ wé e lórí.” Wọ́n bá fi aṣọ mímọ́ wé e lórí, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun, angẹli OLUWA sì dúró tì í. Angẹli náà kìlọ̀ fún Joṣua pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Bí o bá tẹ̀lé ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin mi mọ́, o óo di alákòóso ilé mi ati àwọn àgbàlá rẹ̀. N óo sì fún ọ ní ipò láàrin àwọn tí wọ́n dúró wọnyi. Gbọ́ nisinsinyii, ìwọ Joṣua, olórí alufaa, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin alufaa alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, ẹ̀yin ni àmì ohun rere tí ń bọ̀, pé n óo mú iranṣẹ mi wá, tí a pè ní Ẹ̀ka. Wò ó! Nítorí mo gbé òkúta kan tí ó ní ojú meje siwaju Joṣua, n óo sì kọ àkọlé kan sórí rẹ̀. Lọ́jọ́ kan ṣoṣo ni n óo mú ẹ̀ṣẹ̀ ilẹ̀ yìí kúrò. Ìran nípa Ọ̀pá Fìtílà. Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ tún pada wá, ó jí mi bí ẹni pé mo sùn. Inú àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí yóo dùn, wọn yóo sì rí okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ Serubabeli. Àwọn fìtílà meje wọnyi ni ojú OLUWA tí ń wo gbogbo ayé.” Mo bá bi í pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn igi olifi meji tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà?” Mo tún bèèrè lẹẹkeji pé, “Kí ni ìtumọ̀ ẹ̀ka olifi meji, tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fèrè wúrà meji, tí òróró olifi ń ṣàn jáde ninu wọn?” Ó tún bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ohun tí wọ́n jẹ́ ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.” Ó bá dáhùn, ó ní, “Àwọn wọnyi ni àwọn meji tí a ti fi òróró yàn láti jẹ́ òjíṣẹ́ OLUWA gbogbo ayé.” Ó bi mí pé kí ni mo rí.Mo dáhùn pé, “Mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà, àwo kan sì wà lórí rẹ̀. Fìtílà meje wà lórí ọ̀pá náà, fìtílà kọ̀ọ̀kan sì ní òwú fìtílà meje. Igi olifi meji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwo náà, ọ̀kan ní apá òsì.” Nígbà náà ni mo bi angẹli náà pé, “OLUWA mi, Kí ni ìtumọ̀ àwọn kinní wọnyi?” Ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ìtumọ̀ wọn ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.” Angẹli náà sọ fún mi pé, “Iṣẹ́ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun rán sí Serubabeli ni pé, ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bíkòṣe nípa ẹ̀mí mi. Kí ni òkè ńlá jámọ́ níwájú Serubabeli? Yóo di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Serubabeli, O óo kọ́ ilé náà parí, bí o bá sì ti ń parí rẹ̀ ni àwọn eniyan yóo máa kígbe pé, “Áà! Èyí dára! Ó dára!” ’ ” OLUWA tún rán mi pé, “Serubabeli tí ó bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé Ọlọrun yìí ni yóo parí rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn eniyan mi yóo mọ̀ pé èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo rán ọ sí wọn. Ìran nípa Ìwé Kíká Tí Ó Ń Fò. Mo tún gbé ojú sókè, mo bá rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú. Mo bi angẹli náà pé, “Níbo ni wọ́n ń gbé e lọ?” Ó dáhùn pé, “Ilẹ̀ Ṣinari ni wọ́n ń gbé e lọ, láti lọ kọ́lé fún un níbẹ̀. Tí wọ́n bá parí ilé náà, wọn yóo gbé e kalẹ̀ sibẹ.” Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé “Mo rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú. Ìwé náà gùn ní ìwọ̀n ogún igbọnwọ, (mita 9); ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½).” Ó bá sọ fún mi pé, “Ègún tí yóo máa káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà ni a kọ sinu ìwé yìí. Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹnikẹ́ni tí ó bá jalè ati ẹnikẹ́ni tí ó bá búra èké, a óo yọ orúkọ rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ náà.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo rán ègún náà lọ sí ilé àwọn olè ati sí ilé àwọn tí wọn ń búra èké ní orúkọ mi. Yóo wà níbẹ̀ títí yóo fi run ilé náà patapata, ati igi ati òkúta rẹ̀.” Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá jáde, ó ní, “Gbé ojú rẹ sókè kí o tún wo kinní kan tí ń bọ̀.” Mo bèèrè pé, “Kí ni èyí?” Ó dáhùn pé, “Agbọ̀n òṣùnwọ̀n eefa kan ni. Ó dúró fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jákèjádò ilẹ̀ yìí.” Nígbà tí wọ́n ṣí ìdérí òjé tí wọ́n fi bo agbọ̀n náà kúrò lórí rẹ̀, mo rí obinrin kan tí ó jókòó sinu eefa náà. Angẹli náà sọ pé “Ìwà ìkà ni obinrin yìí dúró fún.” Ó ti obinrin náà pada sinu agbọ̀n eefa náà, ó sì fi ìdérí òjé náà dé e mọ́ ibẹ̀ pada. Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí àwọn obinrin meji tí wọn ń fi tagbára tagbára fò bọ̀, ìyẹ́ apá wọn dàbí ìyẹ́ ẹyẹ àkọ̀. Wọ́n hán agbọ̀n náà, wọ́n sì ń fò lọ. Ìran nípa Àwọn Kẹ̀kẹ́ Ogun Mẹrin. Mo tún gbé ojú sókè, mo rí kẹ̀kẹ́ ogun mẹrin tí ń bọ̀ láàrin òkè meji; òkè idẹ ni àwọn òkè náà. “Lára àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ti oko ẹrú Babiloni dé, mú Helidai, Tobija ati Jedaaya lẹsẹkẹsẹ, kí o lọ sí ilé Josaya ọmọ Sefanaya. Gba fadaka ati wúrà lọ́wọ́ wọn, kí o fi ṣe adé, kí o sì fi adé náà dé Joṣua olórí alufaa, ọmọ Jehosadaki lórí. Kí o sì sọ ohun tí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí fún un, pé, ‘Wò ó! Ọkunrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka ni yóo gba ipò rẹ̀, òun ni yóo sì kọ́ ilé OLUWA. Òun gan-an ni yóo kọ́ ọ, tí yóo sì gba ògo ati ẹ̀yẹ tí ó yẹ fún ọba, yóo sì jọba lórí ìtẹ́ rẹ̀. Yóo ní alufaa gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn, wọn yóo sì máa ṣiṣẹ́ pọ̀ ní alaafia.’ Adé náà yóo wà ní ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí fún Helidai ati Tobija ati Jedaaya ati Josaya, ọmọ Sefanaya. “Àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn réré yóo wá láti ba yín kọ́ ilé OLUWA. Ẹ óo wá mọ̀ dájú pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó rán mi si yín. Gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹ patapata bí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́.” Àwọn ẹṣin pupa ni wọ́n ń fa kẹ̀kẹ́ ogun àkọ́kọ́, àwọn ẹṣin dúdú ń fa kẹ̀kẹ́ ogun keji, ẹṣin funfun ń fa ẹkẹta, àwọn tí wọn ń fa ẹkẹrin sì jẹ́ kàláńkìnní. Mo bi angẹli náà pé, “Oluwa mi, kí ni ìtumọ̀ ìwọ̀nyí?” Angẹli náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ń lọ sí igun mẹrẹẹrin ayé lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn han Ọlọrun ẹlẹ́dàá gbogbo ayé.” Àwọn ẹṣin dúdú ń fa kẹ̀kẹ́ tiwọn lọ sí ìhà àríwá, àwọn ẹṣin funfun ń lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, àwọn tí wọ́n jẹ́ kàláńkìnní ń lọ sí ìhà gúsù. Bí àwọn ẹṣin tí wọ́n jẹ́ kàláńkìnní ti jáde, wọ́n ń kánjú láti lọ máa rin ayé ká. Angẹli náà bá pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ; wọ́n sì lọ. Angẹli náà bá ké sí mi, ó ní, “Àwọn ẹṣin tí wọn ń lọ sí ìhà àríwá ti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ nípa ibẹ̀.” OLUWA pàṣẹ fún mi pé, OLUWA Kọ Ààwẹ̀ Àgàbàgebè. Ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹsan-an, tíí ṣe oṣù Kisilefi, ní ọdún kẹrin ìjọba Dariusi, ni OLUWA rán mi níṣẹ́ yìí. Ẹ má máa fi ìyà jẹ àwọn opó, tabi àwọn aláìníbaba, tabi àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin yín, tabi àwọn aláìní. Ẹ má máa gbèrò ibi sí ẹnikẹ́ni.” Ṣugbọn àwọn eniyan kò gbọ́, wọ́n ṣe oríkunkun, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ tèmi. Wọ́n ṣe agídí, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ òfin ati ọ̀rọ̀ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun fi agbára ẹ̀mí rẹ̀ rán sí wọn, láti ẹnu àwọn wolii. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun bínú sí wọn gidigidi. “Nígbà tí mo pè wọ́n, wọn kò gbọ́, nítorí náà ni n kò fi ní fetí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí. Bí ìjì líle tí ń fọ́n nǹkan káàkiri bẹ́ẹ̀ ni mo fọ́n wọn ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì. Ilẹ̀ dáradára tí wọ́n fi sílẹ̀ di ahoro, tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnikẹ́ni níbẹ̀ mọ́.” Àwọn ará Bẹtẹli rán Ṣareseri ati Regemumeleki ati gbogbo àwọn eniyan wọn lọ sí ilé OLUWA; wọ́n lọ wá ojurere OLUWA, wọn sì lọ bèèrè lọ́wọ́ àwọn alufaa ilé OLUWA, àwọn ọmọ ogun ati àwọn wolii pé, “Nígbà wo ni a óo dẹ́kun láti máa ṣọ̀fọ̀, ati láti máa gbààwẹ̀ ní oṣù karun-un bí a ti ń ṣe láti ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn?” OLUWA àwọn ọmọ ogun bá rán mi pé, “Sọ fún gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà ati àwọn alufaa pé, nígbà tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀, tí ẹ sì ń ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karun-un ati oṣù keje fún odidi aadọrin ọdún, ṣé èmi ni ẹ̀ ń gbààwẹ̀ fún? Tabi nígbà tí ẹ̀ ń jẹ tí ẹ sì ń mu, kì í ṣe ara yín ni ẹ̀ ń jẹ tí ẹ̀ ń mu fún?” Nígbà tí nǹkan fi ń dára fún Jerusalẹmu, tí eniyan sì pọ̀ níbẹ̀, ati àwọn ìlú agbègbè tí ó yí i ká, ati àwọn ìlú ìhà gúsù ati ti ẹsẹ̀ òkè ní ìwọ̀ oòrùn; ṣebí àwọn wolii OLUWA ti sọ nǹkan wọnyi tẹ́lẹ̀? OLUWA tún rán Sakaraya kí ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọdọ̀ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́, kí ẹ sì fi àánú ati ìyọ́nú hàn sí ara yín. Ọlọrun ṣèlérí láti Dá Ibukun Jerusalẹmu Pada. OLUWA àwọn ọmọ ogun tún bá mi sọ̀rọ̀ pé Nítorí ṣáájú àkókò náà, kò sí owó iṣẹ́ fún eniyan tabi ẹranko, eniyan kò sì lè rin ìrìn àjò láìléwu; nítorí àwọn ọ̀tá tí wọ́n wà káàkiri, nítorí mo mú kí olukuluku lòdì sí ẹnìkejì rẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, n kò ní ṣe sí àwọn eniyan yòókù yìí bí mo ti ṣe sí àwọn ti iṣaaju. Alaafia ni wọn yóo fi gbin èso wọn, àjàrà wọn yóo so jìnwìnnì, òjò yóo rọ̀, ilẹ̀ yóo sì mú èso jáde. Àwọn eniyan mi tí ó ṣẹ́kù ni yóo sì ni gbogbo nǹkan wọnyi. Ẹ̀yin ilé Juda ati ilé Israẹli, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ yín ni àwọn eniyan fi ń ṣépè lé àwọn mìíràn tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbà yín, ẹ óo sì di orísun ibukun. Nítorí náà, ẹ mọ́kànle, ẹ má bẹ̀rù.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Gẹ́gẹ́ bí mo ti pinnu láti ṣe yín ní ibi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú, tí n kò sì yí ìpinnu mi pada, bẹ́ẹ̀ ni mo tún pinnu nisinsinyii láti ṣe ẹ̀yin ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda ní rere. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù. Àwọn nǹkan tí ó yẹ kí ẹ máa ṣe nìyí: ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ nílé ẹjọ́; èyí ni yóo máa mú alaafia wá. Ẹ má máa gbèrò ibi sí ara yín, ẹ má sì fẹ́ràn ìbúra èké, nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni mo kórìíra.” OLUWA àwọn ọmọ ogun tún bá Sakaraya sọ̀rọ̀, ó ní, “Ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà ní oṣù kẹrin, oṣù karun-un, oṣù keje, ati oṣù kẹwaa yóo di àkókò ayọ̀ ati inú dídùn ati àkókò àríyá fun yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ ati alaafia. Òun fẹ́ràn àwọn ará Sioni; nítorí náà ni inú òun ṣe ru sí àwọn ọ̀tá wọn. “Ọ̀pọ̀ eniyan yóo ti oríṣìíríṣìí ìlú wá sí Jerusalẹmu, àwọn ará ìlú kan yóo máa rọ àwọn ará ìlú mìíràn pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ kíákíá láti wá ojurere OLUWA, ati láti sin OLUWA àwọn ọmọ ogun; ibẹ̀ ni mò ń lọ báyìí.’ Ọpọlọpọ eniyan ati àwọn orílẹ̀-èdè ńlá yóo wá sin OLUWA àwọn ọmọ ogun, wọn óo sì wá wá ojurere rẹ̀ ní Jerusalẹmu. Nígbà tó bá yá, eniyan mẹ́wàá láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè yóo rọ̀ mọ́ aṣọ Juu kanṣoṣo, wọn yóo sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí á máa bá ọ lọ, nítorí a gbọ́ pé Ọlọrun wà pẹlu yín.’ ” Ó ní, òun óo pada sí Sioni, òun óo máa gbé Jerusalẹmu, a óo máa pe Jerusalẹmu ní ìlú olóòótọ́, òkè OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati òkè mímọ́. Àwọn arúgbó lọkunrin, lobinrin, tí wọn ń tẹ̀pá yóo jókòó ní ìgboro Jerusalẹmu, ìta ati òpópónà yóo sì kún fún àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin tí wọn ń ṣeré. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní bí eléyìí bá jẹ́ ohun ìyanu lójú àwọn eniyan yòókù, ǹjẹ́ ó yẹ kí ó jẹ́ ohun ìyanu lójú òun náà? Ó ní òun óo gba àwọn eniyan òun là láti orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìlà oòrùn ati ti ìwọ̀ rẹ̀, òun óo mú wọn pada wá sí Jerusalẹmu láti máa gbébẹ̀; wọn óo jẹ́ eniyan òun, òun náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn, lóòótọ́ ati lódodo. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ ṣara gírí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii tí ń sọ láti ìgbà tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun lélẹ̀, kí ẹ baà lè kọ́ ilé náà parí. Ìdájọ́ lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Wọ́n Wà ní Agbègbè Israẹli. OLUWA ní ilẹ̀ Hadiraki yóo jìyà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìlú Damasku. Nítorí pé OLUWA ló ni àwọn ìlú Aramu, bí ó ti ni àwọn ẹ̀yà Israẹli. OLUWA ní, òun óo kó kẹ̀kẹ́ ogun kúrò ní Efuraimu,òun óo kó ẹṣin ogun kúrò ní Jerusalẹmu,a óo sì ṣẹ́ ọfà ogun.Yóo fún àwọn orílẹ̀-èdè ní alaafia,ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ láti òkun dé òkunati láti odò Yufurate títí dé òpin ayé. Ìwọ ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ tí mo fi bá ọ dá majẹmu,n óo dá àwọn eniyan rẹ tí a kó lẹ́rú sílẹ̀ láti inú kànga tí kò lómi. Ẹ pada sí ibi ààbò yín,ẹ̀yin tí a kó lẹ́rú lọ tí ẹ sì ní ìrètí;mo ṣèlérí lónìí pé,n óo dá ibukun yín pada ní ìlọ́po meji. Nítorí mo ti tẹ Juda bí ọrun mi,mo sì ti fi Efuraimu ṣe ọfà rẹ̀.Ìwọ Sioni, n óo lo àwọn ọmọ rẹ bí idà,láti pa àwọn ará Giriki run,n óo sì fi tagbára tagbára lò yínbí idà àwọn jagunjagun. OLUWA yóo fara han àwọn eniyan rẹ̀,yóo ta ọfà rẹ̀ bíi mànàmáná.OLUWA Ọlọrun yóo fọn fèrè ogunyóo sì rìn ninu ìjì líle ti ìhà gúsù. OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dáàbò bo àwọn eniyan rẹ̀.Wọn óo borí àwọn ọ̀tá wọn,wọn óo fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn,ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn bíi ti ẹran ìrúbọ,tí a dà sórí pẹpẹ,láti inú àwo tí wọ́n fi ń gbe ẹ̀jẹ̀ ẹran. Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n,bí ìgbà tí olùṣọ́-aguntan bá gba àwọn aguntan rẹ̀.Wọn óo máa tàn ní ilẹ̀ rẹ̀,bí òkúta olówó iyebíye tíí tàn lára adé. Báwo ni ilẹ̀ náà yóo ti dára tó, yóo sì ti lẹ́wà tó?Ọkà yóo sọ àwọn ọdọmọkunrin di alágbáraọtí waini titun yóo sì fún àwọn ọdọmọbinrin ní okun. Tirẹ̀ ni ilẹ̀ Hamati tí ó bá Israẹli pààlà. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìlú Tire ati Sidoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ìlú Tire ti mọ odi ààbò yí ara rẹ̀ ká, ó ti kó fadaka jọ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ó sì rọ́ wúrà jọ bíi pàǹtí láàrin ìta gbangba. Ṣugbọn OLUWA yóo gba gbogbo ohun ìní Tire, yóo kó gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ dà sinu òkun, iná yóo sì jó o ní àjórun. Ìlú Aṣikeloni yóo rí i, ẹ̀rù yóo sì bà á, ìlú Gasa yóo rí i, yóo sì máa joró nítorí ìrora. Bákan náà ni yóo rí fún ìlú Ekironi, nítorí ìrètí rẹ̀ yóo di òfo. Ọba ìlú Gasa yóo ṣègbé, ìlú Aṣikeloni yóo sì di ahoro. Oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ni yóo máa gbé Aṣidodu; ìgbéraga Filistia yóo sì dópin. N óo gba ẹ̀jẹ̀ ati ohun ìríra kúrò ní ẹnu rẹ̀, àwọn tí yóo kù ninu wọn yóo di ti Ọlọrun wa; wọn yóo dàbí ìdílé kan ninu ẹ̀yà Juda, ìlú Ekironi yóo sì dàbí ìlú Jebusi. Ṣugbọn n óo dáàbò bo ilé mi, kí ogun ọ̀tá má baà kọjá níbẹ̀; aninilára kò ní mú wọn sìn mọ́, nítorí nisinsinyii, èmi fúnra mi ti fi ojú rí ìyà tí àwọn eniyan mi ti jẹ. Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni!Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu!Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín;ajagun-ṣẹ́gun ni,sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn. Ọjọ́ Ìdájọ́ Ọlọrun. Èyí ni iṣẹ́ tí Ọlọrun rán Sefanaya, ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedalaya, ọmọ Amaraya, ọmọ Hesekaya ní àkókò ìjọba Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda. OLUWA ní, “Ní ọjọ́ náà, ariwo ńlá ati ìpohùnréré ẹkún yóo sọ ní Ẹnubodè Ẹja ní Jerusalẹmu; ní apá ibi tí àwọn eniyan ń gbé, ati ariwo bí ààrá láti orí òkè wá. Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Mota, ní Jerusalẹmu; nítorí pé àwọn oníṣòwò ti lọ tán patapata; a ti pa àwọn tí ń wọn fadaka run. “Ní àkókò náà ni n óo tanná wo Jerusalẹmu fínnífínní, n óo jẹ àwọn ọkunrin tí wọ́n rò pé àwọn gbọ́n lójú ara wọn níyà, àwọn tí ń sọ ninu ọkàn wọn pé, ‘kò sí ohun tí Ọlọrun yóo ṣe.’ A óo kó wọn lẹ́rù lọ, a óo sì wó ilé wọn lulẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ kọ́ ọpọlọpọ ilé, wọn kò ní gbébẹ̀; bí wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà, wọn kò ní mu ninu waini rẹ̀.” Ọjọ́ ńlá OLUWA súnmọ́lé, ó súnmọ́ etílé, ó ń bọ̀ kíákíá. Ọjọ́ náà yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn akikanju ọkunrin yóo kígbe lóhùn rara. Ọjọ́ ibinu ni ọjọ́ náà yóo jẹ́, ọjọ́ ìpọ́njú ati ìrora, ọjọ́ ìyọnu ati ìparun, ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́, ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri. Ọjọ́ ipè ogun ati ariwo ogun sí àwọn ìlú olódi ati àwọn ilé-ìṣọ́ gíga. N óo mú hílàhílo bá ọmọ eniyan, kí wọ́n baà lè rìn bí afọ́jú. Nítorí pé wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóo ṣàn dànù bí omi, a óo sì sọ ẹran ara wọn nù bí ìgbẹ́. Fadaka ati wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́jọ́ ibinu OLUWA, gbogbo ayé ni yóo jó àjórun ninu iná owú rẹ̀; nítorí pé yóo mú òpin dé bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé orílẹ̀ ayé. OLUWA ní, “N óo pa gbogbo nǹkan tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé run: ati eniyan ati ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, ati gbogbo ẹja. N óo bi àwọn eniyan burúkú ṣubú; n óo pa eniyan run lórí ilẹ̀. “N óo na ọwọ́ ibinu mi sí ilẹ̀ Juda, ati sí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. N óo pa gbogbo oriṣa Baali tí ó kù níhìn-ín run, ati gbogbo àwọn babalóòṣà wọn; ati àwọn tí ń gun orí òrùlé lọ láti bọ oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀. Wọ́n ń sin OLUWA wọ́n sì ń fi orúkọ rẹ̀ búra wọ́n sì tún ń fi oriṣa Milikomu búra; àwọn tí wọ́n ti pada lẹ́yìn OLUWA, tí wọn kò wá a, tí wọn kì í sì í wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.” Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA Ọlọrun! Nítorí ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé; OLUWA ti ṣètò ẹbọ kan, ó sì ti ya àwọn kan sọ́tọ̀, tí yóo pè wá jẹ ẹ́. Ní ọjọ́ ìrúbọ OLUWA, “N óo fi ìyà jẹ àwọn alákòóso ati àwọn ọmọ ọba, ati àwọn tí ń fi aṣọ orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Ní ọjọ́ náà, n óo jẹ àwọn tí ń fo ẹnu ọ̀nà kọjá bí àwọn abọ̀rìṣà níyà, ati àwọn tí ń fi ìwà ipá, ati olè jíjà kó nǹkan kún ilé oriṣa wọn.” Ìpè sí Ìrònúpìwàdà. Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ gbìmọ̀ pọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí kò ní ìtìjú. Wọn yóo sì gba ilẹ̀ wọn, ohun tí yóo dé bá wọn nìyí nítorí ìgbéraga wọn, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn eniyan èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n ń fi wọ́n fọ́nnu. OLUWA óo dẹ́rùbà wọ́n, yóo sọ gbogbo oriṣa ilé ayé di òfo, olukuluku eniyan yóo sì máa sin OLUWA ní ààyè rẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ̀yin ará Etiopia, n óo fi idà mi pa yín. Èmi OLUWA yóo dojú ìjà kọ ìhà àríwá, n óo pa ilẹ̀ Asiria run; n óo sọ ìlú Ninefe di ahoro, ilẹ̀ ibẹ̀ yóo sì gbẹ bí aṣálẹ̀. Àwọn agbo ẹran yóo dùbúlẹ̀ láàrin rẹ̀, ati àwọn ẹranko ìgbẹ́, àwọn ẹyẹ igún ati òòrẹ̀ yóo sì máa gbé inú olú-ìlú rẹ̀. Ẹyẹ òwìwí yóo máa dún lójú fèrèsé, ẹyẹ ìwò yóo máa ké ní ibi ìpakà wọn tí yóo dahoro; igi kedari rẹ̀ yóo sì ṣòfò. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ìlú tí ó jókòó láìléwu, tí ń fọ́nnu wí pé, “Kò sí ẹlòmíràn mọ́, àfi èmi nìkan.” Wá wò ó, ó ti dahoro, ó ti di ibùgbé fún àwọn ẹranko burúkú! Gbogbo àwọn tí wọn ń gba ibẹ̀ kọjá ń pòṣé, wọ́n sì ń mi orí wọn. Kí á tó fẹ yín dànù, bí ìgbà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ ìyàngbò káàkiri, kí ibinu Ọlọrun tó wá sórí yín, kí ọjọ́ ìrúnú OLUWA tó dé ba yín. Ẹ wá OLUWA, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́; ẹ jẹ́ olódodo, ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, bóyá OLUWA a jẹ́ pa yín mọ́ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀. Àwọn eniyan yóo sá kúrò ní ìlú Gasa; ìlú Aṣikeloni yóo dahoro; a óo lé àwọn ará ìlú Aṣidodu jáde lọ́sàn-án gangan, a óo sì tú ìlú Ekironi ká. Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé etí òkun, orílẹ̀-èdè Kereti! Ọ̀rọ̀ OLUWA ń ba yín wí, Kenaani, ilẹ̀ àwọn ará Filistia; n óo pa yín run patapata láìku ẹnìkan. Ilẹ̀ etí òkun yóo di pápá oko fún àwọn darandaran, ati ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo ti máa jẹko. Etí òkun yóo sì di ilẹ̀-ìní fún àwọn ọmọ Juda tí ó kù, níbi tí àwọn ẹran wọn yóo ti máa jẹko, ní alẹ́, wọn yóo sùn sinu àwọn ilé ninu ìlú Aṣikeloni, nítorí OLUWA Ọlọrun wọn yóo wà pẹlu wọn, yóo sì dá ohun ìní wọn pada. OLUWA ní: “Mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àbùkù tí àwọn ará Moabu ń sọ ati bí àwọn ará Amoni tí ń fọ́nnu, bí wọn tí ń fi àwọn eniyan mi ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ń lérí pé àwọn yóo gba ilẹ̀ wọn. Nítorí náà bí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ti wà láàyè, mo búra pé, a óo pa ilẹ̀ Moabu run bí ìlú Sodomu, a óo sì run ilẹ̀ Amoni bí ìlú Gomora, yóo di oko tí ó kún fún igbó ati ihò tí wọ́n ti ń wa iyọ̀, yóo di aṣálẹ̀ títí lae, àwọn eniyan mi tí ó kù yóo kó àwọn ohun ìní wọn tí ó kù.” Ẹ̀ṣẹ̀ Jerusalẹmu ati Ìràpadà Rẹ̀. Ìwọ ìlú ọlọ̀tẹ̀, o gbé! Ìlú oníbàjẹ́ ati aninilára. Láti ọ̀nà jíjìn, níkọjá àwọn odò Etiopia, àwọn ọmọbinrin àwọn eniyan mi tí a fọ́n káàkiri yóo mú ọrẹ ẹbọ wá fún mi. “Ní ọjọ́ náà, a kò ní dójútì yín nítorí ohun tí ẹ ṣe, tí ẹ dìtẹ̀ mọ́ mi; nítorí pé n óo yọ àwọn onigbeeraga kúrò láàrin yín, ẹ kò sì ní ṣoríkunkun sí mi mọ́ ní òkè mímọ́ mi. Nítorí pé, n óo fi àwọn onírẹ̀lẹ̀ ati aláìlera sílẹ̀ sí ààrin yín, orúkọ èmi OLUWA ni wọn yóo gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli kò ní hùwà burúkú mọ́, wọn kò ní purọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì ní bá ẹ̀tàn lẹ́nu wọn mọ́. Wọn yóo jẹ àjẹyó, wọn yóo dùbúlẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n.” Ẹ kọrin sókè, kí ẹ sì hó;ẹ̀yin ọmọ Israẹli!Ẹ máa yọ̀ kí inú yín sì dùn gidigidi,ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! OLUWA ti mú ẹ̀bi yín kúrò,ó sì ti lé àwọn ọ̀tá yín lọ.OLUWA, ọba Israẹli wà lọ́dọ̀ yín;ẹ kò sì ní bẹ̀rù ibi mọ́. Ní ọjọ́ náà, a óo sọ fún Jerusalẹmu pé:“Ẹ má ṣe fòyà;ẹ má sì ṣe jẹ́ kí agbára yín dínkù. OLUWA Ọlọrun yín wà lọ́dọ̀ yín,akọni tí ń fúnni ní ìṣẹ́gun ni;yóo láyọ̀ nítorí yín,yóo tún yín ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ si yín,yóo yọ̀, yóo sì kọrin ayọ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àjọ̀dún.”OLUWA ní:“N óo mú ibi kúrò lórí yín,kí ojú má baà tì yín. N óo wá kọlu àwọn ọ̀tá yín,n óo gba àwọn arọ là,n óo sì kó àwọn tí a ti fọ́nká jọ.N óo yí ìtìjú wọn pada sí ògogbogbo aráyé ni yóo máa bu ọlá fún wọn. Ìlú tí kò gba ìmọ̀ràn ati ìbáwí, tí kò gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí kò sì súnmọ́ Ọlọrun rẹ̀. N óo wá mu yín pada wálé nígbà náà,nígbà tí mo bá ko yín jọ tán:n óo sọ yín di eniyan patakiati ẹni iyì láàrin gbogbo ayé,nígbà tí mo bá dá ire yín pada lójú yín,Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.” Àwọn olóyè rẹ̀ ní ìwọ̀ra bíi kinniun tí ń bú ramúramù; àwọn onídàájọ́ rẹ̀ dàbí ìkookò tí ń jẹ ní aṣálẹ̀ tí kì í jẹ ẹran tí ó bá pa lájẹṣẹ́kù di ọjọ́ keji. Oníwọ̀ra ati alaiṣootọ eniyan ni àwọn wolii rẹ̀, àwọn alufaa rẹ̀ sì ti sọ ohun mímọ́ di aláìmọ́, wọ́n yí òfin Ọlọrun po fún anfaani ara wọn. Ṣugbọn OLUWA tí ó wà láàrin ìlú Jerusalẹmu jẹ́ olódodo, kì í ṣe ibi, kìí kùnà láti fi ìdájọ́ òdodo rẹ̀ hàn sí àwọn eniyan rẹ̀ lojoojumọ. OLUWA wí pé: “Mo ti pa àwọn orílẹ̀-èdè run; ilé-ìṣọ́ wọn sì ti di àlàpà; mo ti ba àwọn ìgboro wọn jẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè rìn níbẹ̀; àwọn ìlú wọn ti di ahoro, láìsí olùgbé kankan níbẹ̀. Mo ní, ‘Dájúdájú, wọn óo bẹ̀rù mi, wọn óo gba ìbáwí, wọn óo sì fọkàn sí gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún wọn.’ Ṣugbọn, ń ṣe ni wọ́n ń múra kankan, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ibi.” Nítorí náà, OLUWA ní, “Ẹ dúró dè mí di ọjọ́ tí n óo dìde bí ẹlẹ́rìí. Mo ti pinnu láti kó àwọn orílẹ̀-èdè ati àwọn ìjọba jọ, láti jẹ́ kí wọn rí ibinu mi, àní ibinu gbígbóná mi; gbogbo ayé ni yóo sì parun nítorí ìrúnú gbígbóná mi. “N óo wá yí ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè pada nígbà náà, yóo sì di mímọ́, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ èmi OLUWA, kí wọ́n sì sìn mí pẹlu ọkàn kan.