ORÍKÌ ORÍLẸ̀ ÒǸDÓ NÍ ÌLÀNÀ sociology theory of Literature ADÉDÈJÌ, ADÉNÍKẸ̀Ẹ́ TÓSÌN O7/15CC003 APÁ KAN IṢẸ́ ÀṢEKÁGBÁ FÚN Ẹ̀KỌ́ ÀKÀGBOYÈ NÍNÚ ÌMỌ̀ ÌPÌLẸ̀ Ẹ̀DÁ (Bii Eè) NÍNÚ ÈDÈ YORÙBÁ NÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁ-ÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ, YUNIFÁSÍTÌ ÌLỌRIN, ÌLỌRIN, NÀÌJÍRÍÀ. OṢÙ ÈBÌBÌ (MAY), ỌDÚN 2011. ÌFỌWỌ́SÍ Iṣẹ́ àkànṣe yìí ni a ti kà tí a sì rí i pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Nàìjíríà, Yunifásítì Ìlọrin, Ìlọrin. ................................... ......................... ALÀGBÀ ÒKÉWÁNDÉ, O.T. ỌJỌ́ ALÁBÒÓJÚTÓ ................................... ......................... OLÙYẸ̀WÒ ÌTA ỌJỌ́ .................................... ......................... Ọ̀JỌ̀GBỌ́N A.S. ABDUSSALAM ỌJỌ́ OLÓRÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁ- ÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ÌFISỌRÍ Mo fi ìwé yìí sọrí ọba àwọn ọba, Àìkú, Àìsá, Atẹ́rẹrẹ káríayé, ògbìgbà tí í gba aláìlárá, Ẹlẹ́rù níyìn, ọba tó ń gba aláìlẹ́ni kan, ají-pọjọ́-ikú-dà yaágbóyaájù ọkùnrin ogun Ajagungbadé, ọba ìyanu, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin fún dídà tí ó da mi sí dọjọ́ òní. Àti Àwọn òbí mi, ọ̀gbẹ́ni àti ìyáàfin Adédèjì fún akitiyan wọn lórí mi láti le jẹ́ kí ń jẹ́ ènìyàn láyé. Ẹ ṣeun. ÌDÚPẸ́ Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọba, Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run, awímáyẹhùn, òwí bẹ́ẹ̀, ṣe bẹ́ẹ̀, Ẹ́kùn ọkọ Fáráò, Adúró gbọin gbọin lẹ́yìn aṣòótọ́. Òun ni o ràn’mọ níṣẹ́ fàyà tì í. Ọba tó fún mi ni àṣeyọrí tó lógo nínú ẹ̀kọ́. Òun ló tún mú kí iṣẹ́ ìwádìí mi gúnlẹ̀ láyọ̀. Bákan náà, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ bàbá àti ìyá mi fún àtìlẹ́yìn sùúrù, ìjìyà àti ìtọ́jú wọn lórí mi. Ẹ ṣeun púpọ̀, oúnjẹ ọmọ á jiná fún-un yín jẹ ní orúkọ Jésù ẹ kò ni ṣe àṣedànù. Ẹni ẹlẹ́ni kò sì ni gbà ṣe yín ṣe. Ọpẹ́ pàtàkì mi tún lọ sọ́dọ̀ alábójútó iṣẹ́ mi ọ̀gbẹ́ni Okewande Olúwọlé Tẹ́wọ́gboyè fún akitiyan wọn láti mú kí iṣẹ́ ìwádìí mi yìí yọrí sí rere. Ẹ ṣeun, ẹ kú iṣẹ́ mi. Ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀gá mi alàgbà Wàlé Rafiu, Alàgbà Ọmọlayọ̀ Ògúnlọlá, Alàgbà Friday Ọ̀tún, Ọ̀mọ̀wé Adéyẹmí, èmi kò ní gbàgbé yín. Ẹ ṣeun. Ọpẹ́ mi tún lọ sí ọ̀dọ̀ abẹ́nà-ìmọ̀ mi Chief Akinbinuade (J.P.) Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi gbogbo. Aya Ọlánírègún, Jọkẹ́ Adédèjì àti Seun Adèdèjì. Bákan náà, mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn akẹgbẹ́ mi gbogbo; mo sì tún dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n yìí: Ọláníran Láídé, Akínpẹ̀lú Abímbọ́lá, Aj’ibóyè Ọmọ́wùnmí, Tọ́pẹ́ Ràmọ́nù, Abíọ́lá, Folúkẹ́, Bùsáyọ̀ àti Abíọ́dún. ÀṢAMỌ̀ Nígbà tó jẹ́ wí pé afìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ hàn ni lítíréṣọ̀, kókó ohun tí a gbéyẹ̀wò nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni ewì alohùn Yorùbá láti fa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ yọ. Àwùjọ tí iṣẹ́ yìí sì dálé lórí ni àwùjọ ìlú Òndó. Nínú iṣẹ́ yìí oríkì àwọn ọba ìlú Òndó ni a gbé yẹ̀wò oríṣìíríṣìí ọgbọ́n ìwádìí ni a sì ṣe àmúlò rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò le ṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ kan bí i ewì láìṣe àmúlò tíọ́rì kan tàbí àtinúdá. Tíọ́rì tí a ṣe àmúlò nínú iṣẹ́ yìí ni tíọ́rì Ṣosíọ́lọ́jì lítíréṣọ̀. Bákan náà a ṣe ìgbéléwọn àwọn oríkì ọba ìlú Òndó láti mọ àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí, a sì tún fi àwọn oníṣẹ́ akadá tó ń bọ̀ lẹ́yìn ní ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú. ÀTẸ ÀKÓÓNÚ Àkọlé i Ìfọwọ́sí ii Ìfisọrí iii Ìdúpẹ́ iv Àṣamọ̀ vi Àtẹ Àkóónú vii ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ 1.0 Ìfáàrà 1 1.1 Èrèdí iṣẹ́ ìwádìí 2 1.2 Ibi tí ìwádìí gbòròò dé 3 1.3 Ọgbọ́n ìwádìí 3 1.4 Àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí yìí 5 1.5 Ètò ìwádìí 5 ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN 2.0 Ìfáàrà 6 2.1 Oríkì ní àwùjọ Yorùbá 6 2.2 Oríkì orílẹ̀ 11 2.3 Ìbáṣepọ̀ láàárín oríkì àti lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá mìíràn 13 2.4 Tíọ́rì 18 2.5 Tíọ́rì Ìṣàmúlò: Tíọ́rì Ìfojú-ìmọ̀ ìbára-ẹni-gbépọ̀-láwùjọ- wo-iṣẹ́ lítíréṣọ̀ 21 ORÍ KẸ́TA ÀWÙJỌ TÓ BÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ: ÌLÚ ÒǸDÓ 3.0 Ìfáàrà 27 3.1 Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Òǹdó 27 3.2 Àlàyé lórí oríkì orílẹ̀ Òǹdó 32 3.3 Oríkì àwọn Ọba kọ̀ọ̀kan 35 3.4 Àwọn ọba tó ti jẹ àti ọdún wọn 41 3.4 Díẹ̀ nínú ìtàn ìgbésí ayé àwọn ọba ìlú Òǹdó 43 ORÍ KẸ́RIN FÍFI TÍỌ́RÌ ÌBÁGBÉPỌ̀ ÀWÙJỌ Ṣ`ETÚPA LẸ ÀWỌN ORÍKÌ ORÍLẸ̀ ÒǸDÓ 4.0 Ìfáàrà 49 4.1 Àgbéyẹ̀wò ipa àti ipò àwọn ọba ni ìlú Òǹdó 50 4.1.0 Ìgbésẹ̀ ìfinijoyè 52 4.2 Ipa àti ipò Òǹdó nípa ogun jíjà 54 4.2.1 Ipa àti ipò àwọn ọba Òndó gẹ́gẹ́ bí alágbára 55 4.2.2 Ogun jíjà 56 4.2.3 Iṣẹ́ òòjọ́ wọn 57 4.2.4 Ètò ìṣèlú 58 4.3 Ìmúra 60 ORÍ KARÙN-ÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ 5.0 Ìfáàrà 62 5.1 Ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí yìí 63 5.2 Àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí 64 5.3 Ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú 65 5.4 Àgbálọgbábọ̀ 65 Àkójọ orúkọ ìwé 66 ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀SẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ 1.0 ÌFÁÀRÀ Náání, nàànì, náání, ohun a ní làá náání, ìran aṣẹ́gità ní í náání èèpo igi ìran ọmọ Yorùbá a sí máa náání àṣà wọn. Onírúurú bí aṣọ alágẹmọ a ní àṣà tí ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ mọ èyí a fi ń dánilárayá bì í orin, ìtàn àròsọ àti ewì. Nínú gbogbo iṣẹ́ ìwádìí yìí, ewì ni a yàn láàyò. Ẹ̀yà ara ewì alohùn ni oríkì wà oríṣìíríṣìí oríkì sí ni ó sí wà. Bí oríkì ìnágijẹ bọ̀rọ̀kìnní, àníjẹ́, àdájẹ́ oríkì orílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí a ṣe rí oríkì àwọn ohun ti kì í ṣe ènìyàn, ṣùgbọ́n tó jẹ́ ohun abẹ̀mí bí i ẹyẹ, ẹranko àti àwọn ohun ọ̀gbìn mìíràn. Nínú iṣẹ́ yìí oríkì ni a ó máa gbẹ́ yẹ̀wò, kì í sí i ṣe oríkì àwọn ènìyàn lásán, bí kò ṣe oríkì àwọn ọba oríkì àwọn ọba tí a sí ń wí yìí rinlẹ̀ ni àwọn ìlú ilẹ̀ Yorùbá. Ó máa ń fi bí ipò oníkálùkú àwọn ìlú wọ̀nyí ló ní ọ̀nà tí wọn ń gbà gbé oríkì kalẹ̀. Bí àpẹẹrẹ àrà ọ̀tọ̀ ní oríkì ọba ni Ọ̀yọ́. Àwọn apohùn ló máa ń kéwì yìí. Bí a ṣe rí ìgbékalẹ̀ oríkì àwọn ọba ìlú Ọ̀yọ́ náà ni ṣe rí ìgbékalẹ̀ oríkì àwọn ọba ìlú Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú Òǹdó láti mọ ètò láti mọ ètò àṣà àti ìṣẹ̀dá àwọn ẹ̀yà yìí ìlú Òǹdó jẹ́ ẹ̀yà Yorùbá ni ijọbá ìwọ̀ oòrùn ní ìpínlẹ̀ Òǹdó ìlú tí wọ́n bá pààlà ní ìlú Ìkálẹ̀ tí òun náà wà ní abẹ́ ijọbá Gúúṣú ìwọ̀ oòrùn ní ìpínlẹ̀ Òǹdó. 1.1 ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Bí kò bá nídìí obìnrin kì í jẹ́ kúmólú. Ìdí pàtàkì tí a fi dágbálé iṣẹ́ yìí ni láti ṣàfihàn oríkì gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan pàtàkì nínú ọ̀nà tí a ń gbé àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá ga. A wò ó gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan pàtàkì tí a fi ń pa ìtàn ìlú mọ́. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àṣà tí ó rinlẹ̀ ni ìlú Òǹdó. Kò sí ilé àdúgbò, ọlọ́danni tàbí olóyè tí ó wà ni ìlú Òǹdó lónìí tí kò ni oríkì kan tí ó ń fi orísun àti ìhùwàsí wọn hàn. Àtúpalẹ̀ oríkì yóò fún wá ní àǹfààní láti mọ ibi ti wọn ti ṣè wá iṣẹ́ wọn, èèwọ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹ̀yà Yorùbá. Lọ́nà mìíràn orísun wọn àti ìbátan wọn pẹ̀lú ẹ̀yà àti ìlú mìíràn. 1.2 IBI TÍ ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ Nínú iṣẹ́ yìí a ṣe àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ ọnà àtinúdá bì i ewì ní pàtàkì jùlọ oríkì láwùjọ Yorùbá. Iṣẹ́ yìí tan iná wo oríkì tí a le bá pàdé láwùjọ Yorùbá bí i; oríkì orílẹ̀ àti ti ọba. Ṣe okùn kì í gùn kò má ni ibi tí a fàá wà. Iṣẹ́ yìí tọpinpin orírun ìlú Òǹdó tí a ń gbéyẹ̀wò ìdílé kọ̀ọ̀kan tó ti jẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ títí di òní. Síwájú sí i, a ó ṣe àtúpalẹ̀ oríkì orílẹ̀ ní ìlànà tíọ́rì ìfojú ìmọ̀ ìbára-ẹni-gbépọ̀ láwùjọ wo-iṣẹ́ lítíréṣọ̀. Ní àgbálọgbábọ̀ a ó wo àwọn àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí àti ìmọ̀ràn fún ìlò atọ́ka ọjọ́ iwájú. 1.3 ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ Kí èròǹgbà wa lórí ìfojú tíọ́rì ìmọ̀-ìbara-ẹni-gbépọ̀-láwùjọ-wo oríkì orílẹ̀ le di mímú ṣẹ, a gbọdọ̀ ṣe àmúlò ọgbọ́n ìwádìí tó kún tó sí múná dóko ọgbọ́n ìwádìí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti ọgbọ́n ìwádìí líọ sí yàrá ìkówèépamọ́sí. Ọgbọ́n ìwádìí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò jẹ́ ọgbọ́n ìwádìí kan tó ṣe pàtàkì. Ṣe bí ọmọdé kò bá ìtàn dandan ni kí ó bá àrọ́bá. Ẹ̀rọ agbohùn tí a mọ sí téèpù ni a ó lò láti gba ohun òǹkọ̀wé sílẹ̀ kí a tó lọ sí ọ̀dọ̀ abẹ́nà-ìmọ̀ a tí kọ́kọ́ ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìbéèrè tó múnádóko tí a ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ìdí tí a fi lo ẹ̀rọ agbohùn nínú iṣẹ́ yìí ni kí o bà a lé rọrùn fún wa láti rántí ohùn gbogbo tí a bá gbọ́ lẹ́nu abẹ́nà-ìmọ̀. Síwájú sí i, ọgbọ́n ìṣèwádìí mìíràn ni lílọ sí iyàrá ìkówèépamọ́sí. Èyí sí fún wa ní àǹfààní láti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí àwọn onímọ̀ ti ṣe lọ́kan-ó-jọ̀kan lórí iṣẹ́ tó jẹ́ mọ́ iṣẹ́ yìí. A rí àwọn oríṣìíríṣìí ìwé ti àwọn aṣááju tí kọ. Gbogbo ìwọ̀nyí ni yóò ran wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí. 1.4 ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò fún wa ní ìmọ̀ tí o gbòòrò nípa iṣẹ́ ọ̀nà àtinúdá Yorùbá ewì ní pàtàkì oríkì. Iṣẹ́ ìwádìí yìí wà fún ìgbélárúgẹ àṣà àti iṣẹ́ Yorùbá. Ojú abùkù tí àwọn kan fi ń wo ó sì le fi bẹ́ẹ̀ di ohùn ìgbàgbé pátápátá. Bákan náà yóò ṣe àfikún ìmọ̀ nínú oríkì àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá tí a ti mọ tẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ sí ni láti mu kí àwọn oríkì wọ̀n yìí wà lákọọ̀lẹ̀ yóò sí tún ran wá lọ́wọ́ láti mọ ipa, ipò àti ìtàn ìgbé ayé àwọn ọba tó ti jẹ́ ni ìlú Òǹdó. 1.5 ÈTÒ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Orí márùn-ún niṣẹ́ yóò pín sí orí kìíní ni a ti ṣàlàyé ohun tí ó pilẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí gẹ́gẹ́ bí ìfáàrà ibi ni a ó ti sọ̀rọ̀ lórí èrèdí iṣẹ́ yìí ni a ti wọ́n aáyan àwọn ọ̀mọ̀ràn lórí oríkì níbẹ̀ ni a ti wo ohun tí oríkì orílẹ̀ jẹ́. Bákan náà a o wo ohùn tí àwọn aṣáájú ṣe lórí tíọ́rì ìbará-ẹni gbépọ̀-láwùjọ. ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN 2.0 ÌFÁÀRÀ Ohun tí orí kejì iṣẹ́ ìwádìí dálé lórí ni aáyan ọ̀mọ̀ràn lórí oríkì láwùjọ Yorùbá. Bákan náá ni a ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìbáṣepọ̀ láàárín oríkì àti lítíréṣọ̀ alohùn yòókù a ó sí tún ṣàlàyé kíkún nípa tíọ́rì ìṣàmúlò. Tíọ́rì ìmọ̀ ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀. 2.1 ORÍKÌ NÍ ÀWÙJỌ YORÙBÁ Gẹ́gẹ́ bí èrò Ọlábímtán (1986:197) ní “Oríkì jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí a fi ń da ẹni tó bá jẹ́ Yorùbá mọ̀” Ó tẹ̀síwájú láti ṣe àgbéyẹ̀wò oríkì àwọn orúkọ àmútọ̀runwá bí í Táyé, Ìlọ̀rí, Dàda àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èrò rẹ̀ nípa oríkì orílẹ̀ pé: “Ó jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí a fi lè mọ ògidi èdè Yorùbá tó gbámúṣé kún inú oríkì orílẹ̀ fọ́fọ́”. Lọ́nà mìíràn, ó ní: Oríkì orílẹ̀ ma ń rán wa létí ohun tí àtìrandíran bàbá bàbá-ńlá ìran kan ṣe nígbà ayé rẹ̀. Ó ń sọ nípa iwa iṣẹ́ àti akitiyan àwọn tí a bí sínú ìran tàbí orílẹ̀ yìí. Ó tún rán wa létí ìtàn ìpìlẹ̀ wa láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ irú ènìyàn wo ní àwọn bàbá-ńlá wa jẹ́?. Ohun tí ó sọ fún wa pé oríkì orílẹ̀ kì í bo àṣírí ìwà ikà tàbí ìwà rere kan tí àwọn ará wọ̀nyí bá hù. Fún ìdí èyí oríkì jẹ́ orísun ohun àmúyangàn fún ọmọ abínibí Yorùbá. Láṣebìkan (1958:32) ṣàlàyé pé; “It is oríkì which tells where a person originates from how powerful his ancestors were, how wealthy they were, and all the noble things that they had done”. (Oríkì ní í sọ ibi tí ènìyàn ti ṣẹ̀, bí wọ́n ti là tó, àti oríṣìíríṣìí nǹkan akọni tí wọ́n ṣe gbogbo). Ohun tí Láṣebíkan ń sọ ni pé, ọ̀nà kan gbòógì tí a fi lè mọ ènìyàn dunjúdunjú ni nípasẹ̀ oríkì irú ẹní bẹ́ẹ̀, nítorí pé oríkì rẹ̀ yóò túṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀. Ulli Beier àti Gbàdàmọ́sí (1959:12) sọ pé oríkì ni: “A poetic phrase that is used to describe or praise” Ohun tí àwọn onímọ̀ méjèèjì yìí ń sọ ni wí pé, oríkì ni a fi máa ń ṣàpèjúwe ènìyàn tàbí fi gbóríyìn fún ènìyàn. Adéoyè (1972:1-2) sọ pé; A sọ ọmọ ní sọ́de, ó sebí sódẹ̀, a sọ ọmọ ní sóbọ̀, ó lọ àjò, ó bọ. A wá sọ ọmọ ní Sórìnlọ, ó lọ sájò kò mọ pé ilé lọmọ ti mú orúkọ ànù lọ? Kókó ohun tí Adéoyè ń sọ ni pé orúkọ ọmọ ni ìjánu ọmọ. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ wí pé àkíyèsí tó gbọnngbọ́n máa ń wà kí a tó sọ ọmọ lórúkọ nítorí ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn ó máa ń ní ipa lórí ọmọ tàbí ẹbí lápapọ̀ bóyá ní èyí tí ó dára tàbí èyí tí kò dára. Ọlátúnjí (1984:67-105) ṣe àlàyé lẹ́ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa bí oríkì ṣe ṣe pàtàkì tó láwùjọ Yorùbá àti bí ó ṣe jẹ́ ohun èlò tí àwọn ẹ̀yà Yorùbá kò lè ṣe aláìlò nínú ìṣe ojoojúmọ́ wọn. Nínú àkóónú ó sọ báyìí pé; Oríkì is used to define its subject, usually by maximazing those attributes which the Yorùbá society consider to be good qualities and laying down as much as possible. (Oríkì wúlò fún ẹni tí à ń kì nípa ṣíṣe àwọn àbùdá rere tí àwọn Yorùbá kà sí àti ṣíṣe àfẹ́rìí àwọn àbùdá tí kò ṣe é fi yangan) Síwájú sí i, nínú iṣẹ́ rẹ̀ kò ṣàì ṣe àlàyé lórí àwọn oríkì orílẹ̀, oríkì ọlọ́danni, oríkì àwọn ọba ìlú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sì tún jẹ́ kí a mọ̀ wí pé ọ̀nà tí a ń gba gbé àwọn oríkì yìí kalẹ̀ le yàtọ̀ ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn. Dáramọ́lá àti Jẹ́jẹ́ (1967:67-68) sọ̀rọ̀ nípa oríkì, wọ́n ní; Oríkì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí tí àwọn Yorùbá máa ń fi yin ara wọn tàbí ẹni tí inú wọn bá dùn sí. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní kò ní í tán lára ọmọ ọba kó má ku dàńsáákì. Ohun tí a rí fà yọ nínú rẹ̀ ni pé kò le burúburú nínú ìgbà oṣùn kí a má fi pa ọmọ lára, kò le burúburú fún ọmọ ọba kí ó máa ní oríkì bọ̀rọ̀kìnní. Àríwòye olùṣèwádìi ni pé àwọn Yorùbá a tún máa sọ oríkì àdájẹ́, oríkì orílẹ̀ ọmọ. Àríwòye pàtàkì tí a tún rí níbi oríkì orílẹ̀ ni pé ó jẹ́ oríkì kan gbòógì tí ó wà fún ẹ̀dá kan, tọkùnrin, tobìnrin ni ó sì máa ń ní oríkì orílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá. 2.2 ORÍKÌ ORÍLẸ̀ Oríkì orílẹ̀ ni oríkì tí a mọ̀ mọ àwọn oríṣìíríṣìí àwọn ìdílé tí ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá. Ohun mìíràn tí a lè pè ní oríkì orílẹ̀ ni oríkì orírun láti ara oríkì orílẹ̀, gbogbo ohun tí a bá fẹ́ mọ̀ nípa ènìyàn ni ó lè jẹyọ. Adéoyè (1969) sọ pé, ibi tí a bá mọ ọ̀nà dé là á ki ìlú dé. Oríkì orílẹ̀ ṣe àfihàn bí ìran kan ṣe bá ìran kejì tan ní ilẹ̀ Yorùbá. Ibi tí àwọn ìlú kọ̀ọ̀kan ti ṣẹ̀, pàtàkì púpọ̀ nítorí pé ó máa ń ṣe àfihàn bí ìran kan ṣe bá ìran kejì tan ní ilẹ̀ Yorùbá. Ibi tí àwọn ìran kọ̀ọ̀kan ti ṣẹ̀, iṣẹ́ ìdílé ni ó lè jẹ jáde. Bí àpẹẹrẹ nínú oríkì ọkọ̀ ni a ti gbọ́ pé “wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹyẹ ẹ̀gà”, gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó máa ń fara hàn nínú oríkì orílẹ̀. Pàtàkì ni oríkì orílẹ̀ láwùjọ Yorùbá kò sí ìlú kan nílẹ̀ Yorùbá tí kò ní oríkì orílẹ̀. Àpẹẹrẹ bí ìhùwàsí ìlú ṣe lè jáde nínú oríkì ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú oríkì ìlú Ìbàdàn pé; Ìbàdàn ọmọ ajoròsùn Ọmọ afìkarahun fóri mu Ìbàdàn ibi olè gbé ń jàre olóhun. Ẹni tí kò bá gbọ́ àlàyé ọ̀rọ̀ yìí á lérò pé Ìbàdàn ń fara kín olè ni, ṣùgbọ́n ohun tí ó ń ṣe ni pé Ìbàdàn a máa bá ẹni tí ó bá jáfara pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ wí. Yàtọ̀ sí èyí, a tún rí nínú oríkì orílẹ̀ ìlú Òǹdó pé ènìyàn pàtàkì ni wọ́n, ó lọ báyìí pé; Akínbínuadé (2003) Ará ìta Ìjámà Èkímògún, ọmọ aládé igbó Iyẹ magogo ide mu omi Ọmọ lílà mẹ̀ríndínlógún ṣẹ̀yẹ Ohun tí oríkì orílẹ̀ yìí ń tọ́ka sí ni pé, kò sí ààyè fún ọ̀lẹ àti ìmẹ́lẹ́ ní ìlú Òǹdó. Níbi yìí ohun tí a rí fàyọ ni pé oríkì orílẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ìlú, iṣẹ́ àti ìhùwàsí ìlú. Gbogbo ìwọ̀nyí a máa jẹ jáde nínú oríkì nígbà tí àríwòye ènìyàn. Ìrírí àti ẹni tí ó jẹ́ a máa sábà jẹ jáde nínú oríkì àbísọ, àdájẹ́, ìnágijẹ àti bọ̀rọ̀kìnní, ṣùgbọ́n gbogbo oríkì pátá ni ó jẹ́ ara àṣà Yorùbá. 2.3 ÌBÁṢEPỌ̀ LÁÀÁRÍN ORÍKÌ ÀTI LÍTÍRÉṢỌ̀ ALOHÙN YORÙBÁ MÌÍRÀN Láì ṣe àní-àní, ìran Yorùbá lápapọ̀ ló ni àṣà àti ìṣẹ̀ṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wọ́n sì máa ń gbé èyí yọ nínú ìṣe wọn. Èyí ló sún wa dé ibi lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ lítíréṣọ̀ alohùn jẹ́ iṣẹ́ ọnà tó ń ti ìran kan dé ìran kejì. Kò sí ní àkọsílẹ̀ rárá. Èyí ló bí òwe Yorùbá kan tó sọ pé ṣáájú kí àgbàdo tó dáyé ni, adìyẹ ti ní ohun tí ó ń jẹ. Fún ìdí èyí, kí àwọn Òyìnbó aláwọ̀ funfun tó dé ni àwọn ìran Yorùbá ti ní ohun tí wọ́n ń pè ní lítíréṣọ̀ ti wọn. Èyí sì ni lítíréṣọ̀ alohùn. Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá, oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni a lè gbà rí lítíréṣọ̀ mìíràn ti máa ń bá oríkì pàdé. Ìdí ni pé wọn jọ máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wọn. Gbogbo wọn ni ó ń lo oríkì, wọ́n kì í ya ara wọn nígbà kankan bí ti í wù ó mọ, nítorí pé wọ́n ní ìbáṣepọ̀ pẹ́kípẹ́kí. Àpẹẹrẹ díẹ̀ lára àwọn ewì Yorùbá mìíràn tí a ń bá oríkì pàdé ni ìjálá, Ẹkùn ìyàwó, rárà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lára lára àwọn onímọ̀ tó ṣiṣẹ́ lórí ìjálá ni Yémiítàn (1982:1), ó sọ pé; Ìjálá ni àwọn ọdẹ fi máa ń sọ ìtàn oríṣìíríṣìí nípa ògún tàbí nípa ọdẹ ṣíṣe àti gbogbo ohun tí ọdẹ ń fojú rí nínú igbó. Onímọ̀ mìíràn tó tún ṣiṣẹ́ lórí ìjálá ni Babalọlá (1966) nínú rẹ̀ ó sọ pé; Ìjálá ni ewì tí ògún máa lò ní ìgbà ayé rẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ìjálá ní í ṣe pẹ̀lú ògún ní gbogbo ọ̀nà ó jọ ẹni pé àwọn tí wọ́n bá ti ni nǹkan án ṣe pẹ̀lú ògún ni wọ́n máa ń sun ún ìjálá tọkùnrin tobìnrin ló máa ń fi ṣiṣẹ́ ṣe tí àwọn obìnrin sì máa ń sùn-un lọ́ọ̀dẹ̀ wọn láti fi dárayá. Àwọn tí ó jẹ́ àgbàtẹrù rẹ gan-an ni àwọn ọdẹ. Àwọn ọdẹ ló ni ìjálá láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wa. Wọ́n sí máa ki ògún báyìí; Ògún torí obì, o jẹkùú Ìjẹ̀ṣà Ogun jà wọ́n, ogun ò kẹ́rù wọn Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ ṣáájú, wọ́n tún máa ń ki oríkì ẹranko látàrí iṣẹ́ tí wọn ń ṣe tàbí nípa ìhùwàsí wọn. Àpẹẹrẹ ni oríkì “Ẹtu”: Ẹtu lárún Ọ̀bẹ̀jẹ́ ń yẹkẹ A-bi-tete ológún ẹni fa A-bi-ìjànjá í pe alàárù tantan Ẹtu mọ́ṣalá, Ẹtu sàlàkọ́ Òfèfè-nfe, ari’ ru tún raṣọ níwájú ọkọ. Oríkì òkè yìí ń ṣe àlàyé bí “Ẹtu” ṣe rí ni. Ẹtu jẹ́ ẹranko tí kò tóbi, ṣùgbọ́n tí àwọ̀ ara rẹ̀ máa ń dán bọ̀lọ̀jọ̀, ó sì tún jẹ́ ẹni tí ó máa ń sare, ó ní irun lára. Ó sì tún jẹ́ ẹranko tí ó ní afínjú púpọ̀ (ìjálá aré ọdẹ láti ọwọ́ Yémiítàn (1982:65). Bákan náà oríkì òkè yìí ń ṣe àlàyé bí ó ṣe rí. Ọ̀kan lára àwọn ewì alohùn Yorùbá tí a ń rán lẹ́nu ni ìjálá èyí ni a mọ̀ sí Ìsàré. Èyí tí ó túmọ̀ sí pé ọ̀nà ìgbéjáde rẹ̀ ni a fi sọ wọ́n lórúkọ. Babalọlá (1966) ti ṣe onírúurú ìwádìí àkójọpọ̀ àti ìtúpalẹ̀ lórí ìjálá, ohun tó farasin nínú ìjálá ni ìrèmọ̀jé. Àwọn ọdẹ àti àwọn olùsin òrìṣà Ògún ló ni ìjálá. Ìjálá sísun máa ń wáyé lásìkò tí àwọn ọdẹ bá ní ètò pàtàkì ṣe. Ó lè jẹ́ àjọ̀dún ọdẹ tàbí lásìkò tí wọ́n bá ń bọ òrìṣà Ògún. Ìjálá sísun kún fún oríṣìíríṣìí èròǹgbà lítíréṣọ̀. Òun náà sí máa fi àwùjọ Yorùbá hàn dénúdénú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà. Dáramọ́lá àti Jẹ́jẹ́ (1976:5) sọ pé ìjálá kò ṣe fọ sí wẹ́wẹ́ láti fún ni ìtumọ̀ kan pàtó fún ọ̀rọ̀ tí a mọ̀ sí ìjálá. Àwọn ọdẹ a máa dẹ ìgbẹ́ àdẹpọ̀ láti pa ẹran, bóyá nígbà tí ẹnìkan nínú wọn bá ni ohun pàtàkì láti ṣe lásìkò ọdún ọdẹ tàbí ọdún ògún bí wọn bá pa ẹran tán nínú igbó. Wọn a kó ara wọn jọ láti máa jó, àti láti máa fi ìdùnnú wọn hàn. Wọ́n a máa gbóríyìn fún orìṣà ògún pé ó mú kí ọwọ́ wọn yá. Wọ́n a sí máa fi bí agbára ọdẹ ṣíṣe wọn ṣe ga tó hàn. Wọ́n a kí ọdẹ aperin sí erin pípa. Wọn a kí ọdẹ apẹkùn sí ẹkùn pípa pẹ̀lú. Wọ́n a bẹ̀rẹ̀ ìlù àti ijó láti inú igbó títí wọn a fi dé àrín ìlú bí wọ́n ti ń jó bẹ́ẹ̀ ni wọn ó máa yín bọn fún òrìṣà ògún . Oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni a lè gbà pín ewì Yorùbá lọ́nà kan a lè fi ojú ìlò wo ó. Èyí ni àwọn ewì tó jẹ́ ti gbogbogbò tàbí tí ó jẹ́ ti àwùjọ Yorùbá lápapọ̀ bí í ìjálá ìwé tàbí ẹ̀ṣà egúngún, ekún ìyàwó, rárá òkú pípè, òwe, ọfọ̀, òkú pípè òwe ọfọ̀ eṣe ifá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bákan náà ni àwọn kan wà tí ó jẹ́ ti àdúgbò lára wọn ni. Alámọ̀ (Èkìtì) orin ọpa (Ìgbómìnà) olele (ijẹ̀ṣà) orin etíyẹrí Ègè (Ẹgbá) Lọ́nà mìíràn a lè fi ọ̀nà ìgbé jáde pín ewì Yorùbá sí ìsọ̀rí tí a bá ṣe èyí a lè tọ́ka sí ìsọ̀rí wọ̀nyí. Ajẹ́mọrọ ẹnu àpẹẹrẹ oríkì ọfọ̀, òwe àlọ́ àpamọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bákan náà ni a tún rí àwọn ewì tí a ń rán lẹ́nu tí wọn kọjá ọ̀rẹ́ ṣíṣọ pọ́ńbélé àpẹẹrẹ rárà, yùngbà Iwì/Ẹ̀sà egúngún, ìjálá, ìrèmọ̀jé, ìyẹ̀rẹ́-Ifá, òkú-pípè àti àwọn tí o jẹ́ ti àdúgbò bí i olele, àdàmọ́, olúngbé, òsàré ipè, ọpa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 2.4 TÍỌ́RÌ theory Yorùbá bọ wọn ni a kì í sòòṣà lódò kí làbẹlàbẹ̀ mọ́ mọ̀. A kò le ṣe àgbéyẹ̀wò tàbí ṣe iṣẹ́ lámèyítọ́ láì ṣe àmúlò ìlànà kan. Ìlànà kan tí a ṣe àmúlò láti sọ nípa tíọ́rì. Adéyẹmí (2006:8) sọ pé tíọ́rì ni abẹfẹ́lẹ́ ìmọ̀ tí a fi ń la ìfun àti ẹ̀dọ̀ onírúurú iṣẹ́. Ó sọ síwájú sí i pé nínú ìmọ̀ science Sáyẹ́ńsì ni tíọ́rì theory tí jẹyọ àti pé ìwádìí yòówù ti kò bá gùnlé tíọ́rì kan nínú iṣẹ́ rẹ̀, irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ òfútùfẹ́tẹ̀ ni. Ó tún fi kún-un pé tíọ́rì náà tún tí ìlànà kan tí a ti dánwò tí a sì rí i pé ó jẹ́ òótọ́ bákan náà. Ọbafẹ́mi (1997:7) sọ pé Theory is the aesthetic discourse improving disciplines, to achieve a harmony between the artists vision, knowledge or craft, and successful communication (Tíọ́rì ni irinṣẹ́ ìmọ̀ nípa ẹwà lítíréṣọ̀ láti jẹ́ kí ìbáṣepọ̀ ó wà láàárín ìran òǹkọ̀wé, ìmọ̀ọ́nṣe rẹ̀ àti ìbánisọ̀rọ̀ tó péye) Ohun tí Ọbafẹ́mi ń sọ ni pé àwọn ohun èlò fún àlàyé lórí iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ni tíọ́rì jẹ́. Jonathan Cullar (1997:8) sọ báyìí pé “Theory is the criticism in order to keep criticism on courses”. (Tíọ́rì ni lámèyítọ́ tí a ṣe lórí lámèyítọ́ kí iṣẹ́ lámèyítọ́ lè tẹ̀síwàjú) Ọmọniyì (2002:123) ki tíọ́rì báyìí Ìlànà tí à ń tẹ̀lé láti ṣe ìtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ òun ní o dúró bí ìránṣẹ́ tí a ń lò fún ìtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀. Ohun tí Ọmọniyì náà ń sọ ni pé, láìsí tíọ́rì agogo ẹnu lásán ni a máa lù lórí ìtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀. Ọ̀wọ́ méjì ni tíọ́rì yìí pín sí, ọ̀wọ́ kìíní rí tíọ́rì lítíréṣọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí kò ni àjọṣe pẹ̀lú òǹkọ̀wé àwùjọ ni èyí tí ó jẹ́ pé a kò le ya lítíréṣọ̀ kúrò lára àwùjọ. Ìpín kejì yìí ni tíọ́rì tí a fẹ́ ṣe àmúlò nínú. Iṣẹ́ àkànṣe yìí ìyẹn tíọ́rì ìfojú-ìmọ̀-ìbára-ẹni-gbépọ̀ wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀. 2.5 TÍỌ́RÌ ÌFOJÚ-ÌMỌ̀-ÌBÁRA-ẸNI-GBÉPỌ̀-LÁWÙJỌ WO IṢẸ́ LÍTÍRÉṢỌ̀ Láì ṣe àníàní, ó ṣòro kí a tó lè rí oríkì gbé e tán fún Soṣíọ́lọ́jì, ṣùgbọ́n ohun tó jẹ mọ́ ìbáṣẹpọ̀ láàárín wọn, ìrírí àwọn ènìyàn láwùjọ ni ohun tí irú ìrírí àti àjọṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ lè fà bá ẹ̀dá. Soṣíọ́lọ́jì ni ènìyàn, àwùjọ àti ìbágbépọ̀ wọn àti ipa tí irú ìbágbépọ̀ bẹ́ẹ̀ ní lórí àwùjọ. Ó sọ síwájú sí i pé ohun tó jẹ Soṣíọ́lọ́jì lógún jù ni ìgbé-ayé ẹ̀dá, ìwà rẹ̀, èdè rẹ̀ tí ó jẹ òpómúléró fún ìdúró ẹ̀dá láyé nínú èròǹgbà Soṣíọ́lọ́jì ni láti dáhùn àwọn ìbéèrè bí i. Báwo ni àwùjọ ṣe ṣe? Báwo ló ṣe ń ṣiṣẹ́? Kíló fa ìdúró àwùjọ? Kí èyí tó lè ṣe è ṣe ìgbéléwọ̀n a máa wáyé lórí ètò àwùjọ, ètò ọrọ̀ ajé, ètò ìṣèlú àti àwọn nǹkan mìíràn tí ó parapọ̀ jẹ́ ètò àwùjọ. Ohun mìíràn tó tún jẹ Soṣíọ́lọ́jì lógún ni ọ̀nà ìkọ́ni àwùjọ, ìfòye àṣà kọ́mọlẹ́kọ̀ọ́ àti bí oníkalukú bí i ọba, àgbà àgbà àti ọdẹ ìlú lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe ń gba ipa ti yóò kó láwùjọ kí ìlú ba à lè tòrò. Onímọ̀ mìíràn tó tún ki Soṣíọ́lọ́jì ni Caudwell (1977:15) ó sọ báyìí pé: In relation to one another the study of these human relation in a general form is sociology. (Nígbà kan rí àwọn ènìyàn a máa bára wọn ṣe nǹkan pọ. Ìmọ̀ nípa ìbára ẹni ṣe pọ̀ yìí). Ohun tí Caudwell ń wí ni pé ìmọ̀ nípa ìbáṣepọ̀ láwùjọ àwọn ènìyàn ni Soṣíọ́lọ́jì jẹ́. Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìmọ̀ ìbára-gbépọ̀ nìkan ni Soṣíọ́lọ́jì dúró lé, ó tún máa ń ṣe ìwòye onírúurú ìyípadà tí ó dé bá àwùjọ. Àwùjọ lè rọra máa yí padà tàbí kí o yí padà wìrìwìrì, gbogbo èyí ni Soṣíọ́lọ́jì ma ń ṣe ìwádìí rẹ̀. Bákan náà, Bísí Ògúnṣínà (1981:4) ki defined sociology Soṣíọ́lọ́jì báyìí pé: Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ Soṣíọ́lọ́jì jẹ́ àhunpọ̀ nǹkan méjì. Soṣíọ́lọ́jì jẹ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìbákẹ̀-gbẹ́pọ̀ tí ó ní ìbáṣepọ̀ àti ìgbẹ̀yìn fún ohun tí ó ní ìyípadà pẹ̀lú àwọn nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn látàrí ìbáṣepọ̀ tí wọ́n ni sí ara wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ ìbákẹ̀-gbẹ́pọ̀ yòókù. Ohun tí ó jẹ́ Soṣíọ́lọ́jì lógún ni ìgbé ayé ẹ̀dá pẹ̀lú ìrírí ẹ̀dá, ẹ̀dá pẹ̀lú àwọn tó ń tẹ̀lé wọ́n. Ṣùgbọ́n ohun tó jẹ́ ajólórí Soṣíọ́lọ́jì ni àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn inú àwùjọ. Ọ̀kan lára àṣà Yorùbá ni oríkì jẹ́ ìdí nìyí tí a fi lo tíọ́rì yìí fún ṣíṣe ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ yìí. iṣẹ́ àti ìhùwàsí ẹ̀dá ènìyàn àti ohun tí ènìyàn ń ṣe ni àwùjọ ní o wa nínú oríkì, tí a sì ń fi èdè tí ó dùn gbé e jáde. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ pé èdè tó dùn náà ni òpómúléró àṣà àti wí pé àṣà oríkì àti èdè tí a ń lò fi gbé e jáde inú àwùjọ ni gbogbo wọn tí jẹ́ jáde. Èyí ni o mú kí a gbé àtúpalẹ̀ oríkì yìí ka orí tíọ́rì ìfojú-ìbágbépọ̀ àwùjọ wo lítíréṣọ̀. Èyí yóò sí jẹ́ kí a tún ètò àti àṣà ìbá gbẹ́pọ̀ àwùjọ ìlú Òǹdó sí ìta. Ní àfikún, ohun tí a ń sọ ni pé inú àwùjọ kan náà ni ènìyàn, èdè àti àṣà tí jẹ́ jáde, wọ́n sí ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ara wọn. Yálà àṣà ilẹ̀ wa tàbí àṣà àtọ̀húnrìnwá àti àwọn aláṣà fúnra wọn. Inú àwùjọ náà ni gbogbo wọn tí wá. Kò sí àwùjọ kan tí kò ni àṣà àti iṣẹ́ tí ó ń gùnlé. Ìdí nìyí tí a ṣe rí oríkì láti ara àṣà Yorùbá tí àwọn ìran Yorùbá lápapọ̀ sí ń gbé e lárugẹ ní gbogbo ìgbà. Àtọba, àtìjòyè, àtọmọdé, àtàgbà tó jẹ́ ìran tàbí ẹ̀yà Yorùbá pátá ni wọ́n ni oríkì tí wọn, yálà ti àbísọ tàbí ti orílẹ̀ tó jẹ́ tí gbogbogbò, tí ó sì jẹ́ pé inú àwùjọ ni gbogbo wọn tí wá tí ìbáṣepọ̀ tó lọ́ọ̀rìn sí wà láàárín wọn. Ní àwùjọ ìlú Òǹdó tí iṣẹ́ yìí dá lé lórí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ìlú ilẹ̀ Yorùbá àwọn ẹ̀yà Yorùbá náà ló sí wá níbẹ̀. Àwọn àṣà tí a mọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ibẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mo àwọn ìlú ilẹ̀ Yorùbá fẹ́ràn oríkì nínú lítíréṣọ̀ alohùn wọn. Wọn a máa lò ó níbi ayẹyẹ tí wọn bá ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ níbi ìkọ́mọjáde, ìṣìlè, ìgbéyàwó ìfinijoyé, ìsìnkú tàbí lásìkò àwọn ọdún ìbílẹ̀ wọn gbogbo. Oríkì yìí máa ń jẹ́ kí a ni ìmọ̀ nípa ẹní tí o ni oríkì gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú. A ó mọ orírun àwọn babańlá rẹ̀ àti àwọn nǹkan akọni mìíràn tí wọ́n tí gbé ṣe nínú ìran wọn. Bákan náà ó máa ń fi iṣẹ́ òòjọ́, àmúyẹ àti àléébù wọn hàn. Bí a ṣe lè fi ṣe kóríyá fún ènìyàn. Gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rí ni àwọn àwùjọ Yorùbá yòókù pátá náà ni ti àwùjọ ìlú Òǹdó ṣe rí. MÁÀPÙ ÌPÍNLẸ̀ ÒǸDÓ ORÍ KẸ́TA ÀWÙJỌ TÓ BÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌLÚ ÒǸDÓ 3.0 ÌFÁÀRÀ Ní orí kẹ́ta iṣẹ́ iwadiii yìí ni a o ti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọba tó tí jẹ́, ètò ìṣèlú wọn. Àti àwọn ètò mìíràn tí ó ń mú ìlú Òǹdó yọ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ti i yọ ju orí lọ láàárín àwọn ìlú mìíràn. 3.1 ÌTÀN ÌṢẸ̀DÁLẸ̀ ÌLÚ ÒǸDÓ Ìlú Òǹdó jẹ́ ẹ̀yà Yorùbá ni ìjọba ìwọ oòrùn ni ìpínlẹ̀ Òǹdó ìlú tí wọ́n sí bà pààlà ni ìlú Ìkálẹ̀ tí òun náà wà ní abẹ́ ìjọba Gúúṣù ìwọ oorun ni ìpínlẹ̀ Òǹdó. Ní ayé àtijọ́ àwọn ènìyàn rí ìbejì gẹ́gẹ́ bí àmì burúkú, wọ́n sí máa ń pa wọ́n lójú ẹṣẹ̀ tí wọ́n bá ti bí wọn. Ní ayé ìgbà náà ọ̀kan lára ìyàwó Aláàfin Ọ̀yọ́ bí ìbejì, ṣùgbọ́n ọba yìí nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ púpọ̀. Èyí ló mú kí ó gbìyànjú láti dáàbò bo ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ nípa rírán wọn kúrò láàárín ìlú lọ sí ibi tó jìnnà, nígbà tí wọ́n fẹ́ máa lọ sí ìrin àjò yìí. Aláàfin fún wọn ni ẹrú àti àwọn nǹkan mìíràn. Ìtàn sọ fún wá pé nígbà tí wọ́n dé Ilé-Ìfẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀wà wọn. Ọba (Ọọ̀ni) ṣe àdúrà fún wọn, ó sí kọ àwọn ọmọ wọ̀nyí ni ilà, kí o bà le fi dá wọn mọ̀. Wọ́n tẹ̀síwàjú nínú ìrìn àjò wọn. Wọ́n de ibi kan tí a ń pé ní ita ìjámà láti ibẹ̀ wọ́n dé Ẹ̀pẹ́ ẹni tí ó jẹ́ olórí ìlú yìí sí tẹ́wọ́ gbà wọn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ni wa ibi kan tí a mọ̀ sí Ilẹ̀-Olújìí a fi ìgbà tí ó parí sí òkè kan ni Òǹdó tí a mọ sí Òkè Àgunlà. Bí wọn ṣe débi òkè yìí, wọ́n rí èéfín wọ́n sí tẹ̀lé ipa ọ̀nà yìí. wọ́n pàdé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Ẹkiri” ọkùnrin yìí gbà wọ́n tọwọ́-tẹsẹ̀ ó sì mú wọn lọ sí ibi kan tí a pé ni ìjọré ni ìlú Òǹdó. Àwọn ènìyàn ìlú Òǹdó fi ọ̀kan nínú àwọn ìbejì yìí jé ọba àkọ́kọ́ wọ́n sí ń gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn. Bákan náà ni a tún rí ètò ìṣèlú ìlú Òǹdó. Ní ilé Yorùbá, ọ̀nà tí wọn tí ó jé pé ọba ni aláàkóṣo ohun gbogbo ohun tí ó dájú ni wí pé, igi kan kì í dá igbó ṣe. Èyí ni wí pé ni inú àwùjọ kì í ṣe ọba nìkan ni ó máa ń dá àkóso ìlú ṣe ó pọn dandan kí àwọn ìjòyè jé amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tàbí alábàá ṣíṣe pọ̀ pẹ̀lú ọba. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ takun-takun ni àwọn ọba àti ìjòyè tó ti jẹ ní ìlú yìí tí gbé ṣe láti rí i wí pé ìlọsíwájú tàbí ìdàgbàsókè dé bá ìlú Òǹdó. Nínú gbogbo ẹ̀dá kan ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run Yorùbá jẹ́ ẹ̀dá kan tí o kórìra ìwà ọ̀lẹ àti ìmẹ́lẹ́ wọn. Yorùbá gbà pé iṣẹ́ ni oògùn iṣẹ́ wọ́n a máa sọ pé “òṣùpá wù mi ju òkùnkùn, ẹni tí ń ṣiṣẹ́ wùmí ju ọ̀le àti pé aríṣẹ́máṣe ní í sán fùrọ̀ lóògùn. Ìgbàgbọ́ Yorùbá sì ni pé, ènìyàn kò lè mú iṣẹ́ jẹ kí ó sì mú ìṣẹ́ jẹ àti pé àgbàlagbà tí ó bá ń la igi tà, ó ti sinmi rẹ̀ léwe ni, ẹ̀dá tí kò bà sì ṣiṣẹ́ yóò jalè. Ní ìlú Òǹdó, wọn kì í jí kí wọ́n káwọ̀ gbenú gẹ́gẹ́ bí a ti rí ìwà àti iṣẹ́ wọn. Iṣẹ́ ni wọn máa ń múṣe. Akíkanjú àti akin ènìyàn ni a mọ àwọn ará Òǹdó. Onírúurú iṣẹ́ ni wọ́n sí yàn láàyò ní èyí tí o ń mú kí ìlọsíwájú ó máa bà wọn nínú ìlú náà yálà nínú iṣẹ́ ọdẹ ni tàbí nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ èyí tí ó jẹ́ iṣẹ́ àtìrandíran wọn tí ó sì ń mú kí ètò ọrọ̀ ajé wọn ó máa gbòòrò síwájú sí i, tí o sí tún mú ìdàgbàsókè wọ ìlú wọn. Ètò ẹ̀sìn náà kò gbẹ́yìn nínú ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Òǹdó. Ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá ni pé Olódùmarè ni ó dá ayé tí ó sì tẹ̀ ẹ́ dó. Òun náà ló sì dá àwọn ènìyàn síbẹ̀ kí wọ́n sì tún padà wá láti wá jábọ̀. Lẹ́yìn náà àwọn Yorùbá gbà wí pé wọ́n ní láti máa fi orúkọ Olódùmarè sí ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe láyé nítorí pé bí kò bá sí Olódùmarè ni, kò le sí ẹ̀dá kankan. Látàrí èyí ní ó ṣe jẹ́ pé kò sí ẹ̀sìn náà ni ilẹ̀ Yorùbá ti àwọn babańlá wa ń sìn tí wọn kì í ki Olódùmarè níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adẹ́dàá, aṣẹ̀dá àti gẹ́gẹ́ bí ẹni tí í ó fi àṣẹ sọ̀rọ̀, tí ó sì ń fàṣẹ dáhùn sí onírúurú ìbéèrè ti ẹ̀dá bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ìran Yorùbá lápapọ̀ ló ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ké pe Olódùmarè pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé yóò dá àwọn lóhùn èyí yàtọ̀ ni ìlú sí ìlú, ìletò sí ìletò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Irú ìlànà yìí náà ni a rí ní ìlú Òǹdó. Ṣáájú kí ó tó di pé àwọn ẹ̀sìn àjòjì méjèèjì wọ̀lú Òǹdó ni wọ́n tí ó ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe ẹ̀sìn wọn; àti irú ìbọ tí wọ́n máa ń jẹ́sìn fún. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ́ pé ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ẹ̀sìn ìbílẹ̀ náà ló wọ́pọ́ ni ayé tí ìdílé kọ̀ọ̀kan nínú ìlú sí ni òrìṣà ìdílé tí wọ́n ń bọ yàtọ̀ sí òrìṣà tó jẹ́ tí gbogboo gbò bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń ṣe ní ìlú Òǹdó yìí láti ayébáyé. Àpẹẹrẹ irú ọdún bẹ́ẹ̀ ni ọdún Gbélérù, ọdún Ọlọ́kà, ọdún Ìta Mafo, ọdún Agẹmo, ọdún Ògún, ọdún Ajé, ọdún Ọba, ọdún Èkímògún, ọdún Atakùnmọ̀, ọdún Ìfọ̀rẹ́, ọdún Olórí, ọdún Ọba, ọdún Ẹrínlà, ọdún Lódún. Ọdún oirì, òṣémàwé àti otu ni Àjàlé (òkè-ilé) ni agogo mẹ́rin àárọ̀ kò sí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ kí ó tó di àárọ̀. Kété lẹ́yìn èyí ni ẹgbẹ́ òtú yóò máa kúnlẹ̀ fún àdúrà ni ọ̀dọ̀ òṣémàwé ní kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú obìí kọ̀ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òṣémàwé bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ olórí òtu títí kan olóyè kékeré láì ku olóyè kankan. A kò sí gbọdọ̀ tan iná. Wọn kò sí gbọdọ̀ rí ara wọn. Èyí wà fún àdúrà pàtàkì pé ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ọba fẹ́ bẹ̀rẹ̀.. Ọdún Ìfòré. Ní ìgbà ọdún Ìfòré, àwọn olóyè ìlú Òǹdó yóò mú oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn wá fún òṣémàwé. Òṣémàwé yóò mú lára àwọn ènìyàn rẹ̀, yóò gba ìlù fún ayẹyẹ ọdún. Àwọn òpójì, tí a mọ̀ sí (òpò ilé) yóò mú ìkájú ẹja ńlá àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ obì wà fún òṣémàwé. Lẹ́yìn ọgbọ́n ọjọ́ ọdún Ìfòrè àwọn òpòjì yóò gbé obì lọ fún òṣémàwé ọba yóò gún méjìlélógún pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí àti iṣu tí yóò gbé fún Òyìnbó kan tí a mọ̀ sí olóyè gíga Lisa Lóbùn. 3.2 ÀLÀYÉ LÓRÍ ORÍKÌ ORÍLẸ̀ ÒǸDÓ Oríkì orílẹ̀ ní àárín àwọn Yorùbá jé ohun tí o ṣe pàtàkì. Oríkì orílẹ̀ ni àpapọ̀ oríkì àwọn babańlá àti àwọn ìyáńlá tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ìtàn ìdílé olúwarẹ̀, oríkì orílẹ̀ jẹ́ oríkì tí ó ń júwe ìwà, ìṣe, babańlá àti ìyáńlá ẹni tí a ń sọ̀rọ̀ bá wọ̀nyí. A kò le sọ ní pàtó iye àwọn oríkì orílẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n àwọn tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú wọn tó mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, kókó ọ̀rọ̀ tó sì wà nínú oríkì orílẹ̀ ni ìwà ọmọlúàbí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ inú oríkì máa yan ìtàn àtijọ́, àlàyé kíkún yóò sí kù sí ọwọ́ olùwádìí. Ìgbà tí wọ́n bá ń kí ènìyàn ni ọ̀nà pàtàkì ní òwúrọ̀ kùtukùtù bí ọmọ bá ti dòbálẹ̀ tàbí kúnlè láti kí òbí rẹ̀ kú òwúrọ̀. Ìyá yóò lo gbólóhùn mélòó kan láti inú oríkì ìdílé wọn, láti fi ki ọmọ náà tàbí nígbà tí ó bá lọ kí ìbátan àwọn òbí rẹ̀ tí kò rí fún ọjọ́ pípẹ́, tí ìbátan náà ba jẹ́ obìnrin gbàrà tí ó bá tí rí ọmọdé náà ni yóò tẹnu bọ oríkì orílẹ̀ wọn; yóò máa fi oríkì orílẹ̀ kí ọmọdé náà lọ bí ilẹ̀ bí ẹní, ó le máa dẹ́nu dúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti wí pé “ó káre ǹlẹ́” “o kú àtijọ́ gbogbo àwọn ara-ilé ńkọ́?”, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Orí rẹ̀ náà yóò mu ara rẹ̀ a sí yá gágá pẹ̀lú ẹ̀rín múṣẹ́. Bákan náà nígbà tí àgbàlagbà bá ń ṣe àjọyọ̀ ní agboolé rẹ̀ nítorí ohun mìíràn, oríkì orílẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n a máa fi kì í. Síwájú sí i, a tún rí oríkì orílẹ̀ ìlú Òǹdó pé ènìyàn pàtàkì ni wọ́n ó lọ báyìí pé. Ará ìta ìjámà Èkímógún, ọmọ Aládé igbó Ọmọ afi agogo idẹ mú omi Ọmọ onílà mẹ̀ríndínlógún ṣẹ̀yẹ. Bákan náà ni a tún rí àwọn nǹkan to mú oríkì orílẹ̀ Òndó wáyé. Láyé àtijọ́, ogun ni o ya tọkọ-taya. Ogun ní ó ya ìyá pẹ̀lú ọmọ. Bí ọmọdé kò bá sí bá ìtàn ó yẹ kò bá àrọ́bá, àrọ́bá sì ni bàbá ìtàn. Ogun mú lélé lọ ẹ̀gbá alaké ìyá kò bí lélé ni ẹrú, bàbá kò sí sọ ọmọ rẹ̀ ni ìwọ̀fà, Àkúnlẹ̀yàn wọn ló tí wọ́n dé ọkọ ẹrú lóko ẹrú tí lélẹ̀ wà. Ó múra ṣiṣẹ́, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lélé ṣiṣẹ́ kára. Ó sì ra ẹrú tó pọ̀. Lára ẹrú tí lélè tún rà ni mòrẹ̀ tún wà láì mọ. Lélé pa àṣẹ wí pé kí mórẹ̀ máa lọ ògì. Ìgbàkugbà tí mórẹ̀ bá tún lọ ògì ni ó máa ń kọrin tí ó bá sí tí ń kọrin yìí ni àwọn ọmọ olówó rẹ̀ ń fi etí gbọ títí wọ́n fi mọ orin náà kọ. Wọ́n wa ń kọ orin náà ni ojú bàbá wọn (Lélè). Lélè gbọ, ó ṣe hàá ẹnu ya bí àwọn ọmọ rẹ tí ń kọrin wọ́n ṣe àlàyé wí pé ẹrú titun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rà ni o máa ń kọ. Lélè wá pé ẹrú o sí bẹ̀rẹ̀ orúkọ rẹ̀ ẹrú sí dáhùn pé “Morẹ” Lélè wá sọ fún Mòrẹ pé òun ni Lélè àbúrò rẹ̀, mọ̀rẹ̀ náà tún fi hàn wí pé òun ni mọ̀rẹ̀ àti wí pé ìyá wọn ni oólìbàbì. Lélè wá pàsẹ wí pé kí àwọn ẹrú tó kù kí wọ́n pọ́n omi kí wọ́n sí wẹ mọ̀rẹ̀. Ìdí pàtàkì tí a fi ń jẹ oríkì ni wí pé kí a lè mọ ibi tí a ti wa tàbí bí a bá sọnù kí a le rí ara wa padà. 3.3 ORÍKÌ ÀWỌN ỌBA KỌ̀Ọ̀KAN Ní ìlú Òǹdó, yàtọ̀ sí pé àwọn ọba wọn ń jẹ́ oríkì papọ̀. A tún rí díẹ̀ gbà nínú àwọn oríkì bọ̀rọ̀kìnní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Èyí ni oríkì tí àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ fi máa ń kì wọ́n látàrí ohun ribiribi tí wọ́n tí gbé ṣe, àti nípa pé wọ́n jẹ́ akikánjú ènìyàn oríkì bọ̀rọ̀kìnní ọba kọ̀ọ̀kan lọ báyìí ni ṣókí. YÉSÀN Láte fẹ̀fẹ̀ Onísu to ta gbòngbò Ìyá ẹní, aya aláya ṣe sọ Ó le eku wọ́nu ẹgàn pátápátá Ó na aya ẹní túká Ó bi ọmọ ẹbí ní Ọjọ́ dínkù ó ṣe tán olósùn ńlá Ó sùn gàdágbà légbè ọ̀run Ohun tí oríkì yìí ń sọ nípa rẹ̀ ni pé ọba yìí fẹ́ràn iṣẹ́ ọdẹ láìṣeyeméjì rárá. Ó fẹ́ràn láti máa dẹ̀gbẹ́. ORÍKÌ ADÁJÀ A ń wa O fi agogo idẹ mọ tí Eléwù gbòho, onikédìgbò Ó dá títí ọlá Ó gún le egbò Òkè Àlejó Àlajó gba ilé gbé Ádajà, Eléwù gbòho Orílẹ̀ egbé Òkè àlejó ORÍKÌ JOMU Òyàn onídà Òyànyán onimú Ogbogbo létí Ó ṣe ọwọ́ bàbá núdà Egún ńlá o Ó pá ayé run Ó pa ifọ̀ láyìnmí Ó pa onígbọ̀wọ́ Ó dà jẹ ẹran mìmìmì Ó fi ọwọ́ gbọ́ ifá Ó ń àyé láìláì Ó dàgbà lọ́dọ̀ èṣù ORÍKÌ LÓSÙNLÁ Ajágìgì oògùn Olókè mẹ́ta Òkòkò Balógun Ó dúró lókè Ó sọmọ di pùyé pùyè Òkè gbọ́mọ di tilolo Ologun tí kà di Odidi mọndè Ojú ogun láwé sawé ORÍKÌ LÓGBÒSÉRÉ Ató àgbà gbọngbọn Ó kó ẹbí mọ́ra Ó pàlàngà ẹbí Ó mú gogo rẹ̀ ṣe Ó fi pópó nu ojú ORÍKÌ ARÓGBÓ Àgbède onígèlè Ọkọ pupa Ó lọ sòko Elétí arógbó Ọba kú kegun Elete dèyìn Olè lébà onílé Arógbó ilà ṣẹ̀gi ORÍKÌ LÓYÌNMÍ Òkè odò Alájé orùn akingbájìn Ó ṣe pẹ̀lẹ́ Oní pẹ̀lẹ́ Ajerú mo boku ṣenu Òrún to, Ato Ató ọba nífẹ̀ Ìgbésí tọ̀wọ̀-tọ̀wọ̀ Lóyìnmí aláte ìlèkè ÀYÀDÌ Ìyálà lepegun Ó mú aṣọ ọba Ó mú idà, Ó fi idà sẹ́yìn Ó fi idà jẹṣu Ó sojú kókó Alálè, orò tí Sun ọmọ ayé jẹ Àyàdì, légbàdà Ó kò inà léyìn jọyọ ORÍKÌ ÒṢÉMÀWÉ Kábíyèsí àbá ìyé Ikú alaṣẹ Ògbìgbà gbọmọ là Ó la lóni o Ó jìwàjiwa ìlẹ̀kẹ̀ Ó sọkọ àkókó Alagbára jeni níyà Afèrín sí Ikú aláṣẹ èkejì òrìṣà ORÍKÌ AJISÓWÓ Ọtún owó Ọmọ afèrì wọ̀wọ̀ Sọrọ méjì Ajisówó Ọmọ Lísà pátákó Aṣọ orúkọ, oníbàràká Òtẹ̀lú, òrèrú, o fi Owí erú jọba Ará ìgúrì. 3.4 ÀWỌN ỌBA TO TÍ JẸ́ ÀTI ỌDÚN WỌN 1. Pùpùpù 1510-1530 ọdún mẹ́rìnlá 2. Airo 1530-1561 ọdún mọ́kanlélógún 3. Lújù 1561-1590 ọdún mọ́kanlélógún 4. Òkùta 1591-1614 ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n 5. Lúyaré 1614-1630 ọdún mọ́kàndínlógún 6. Fòyì 1630-1649 ọdún mọ́kàndínlógún 7. Léyò 1649-1668 ọdún mọ́kàndínlógún 8. Gbayi 1668-1685 ọdún mẹ́tàdínlógún 9. Liyen 1685-1702 ọdún mẹ́tàdínlógún 10. Bàjùmú 1702-1711 ọdún mẹ́tàdínlógún 11. Aperuwa 1711-1716 ọdún márùn-ún 12. Gbede- Gbede 1716-1716 13. Làmolè 1716-1731 ọdún márùndínlógún 14. Aganmede 1731-1748 ọdún mọ́kànlá 15. Olowolaiye 1748-1759 ọdún mẹ́tàdínlógún 16. Jógundè 1759-1770 ọdún mọ́kànlá 17. Térere 1770-1796 ọdún mẹ́rindínlógún 18. Ajímósó 1786-1802 ọdún mẹ́rindínlógún 19. Árobiréré 1802-1811 ọdún mẹ́sàn-án 20. Ayanlọlá 1811-1814 ọdún mẹ́ta 21. Ọdúnọla 1814-1817 ọdún márùn-ún 22. Jílù 1817-1822 ọdún márùn-ún 23. Olówólakun 1822-1826 ọdún márùn-ún 24. Jíwòmó 1826-1833 ọdún méje 25. Jílàlá 1833-1844 ọdún mọ́kànlá 26. Jímósùn 1844-1853 ọdún mẹ́sàn-án 27. Afunbiye ọ̀dúndún 1853-1861 ọdún méje 28. Arílékọ́lásì 1861-1866 ọdún márùn-ún 29. Jímosùn 1866-1870 ọdún mẹ́rin 30. Ọ̀ṣungbádelọlá 1870-1873 ọdún mẹ́ta 31. Ayíbíkíwòdì 1873-1876 ọdún márùn-ún 32. Afàìdùnóyè 1876-1881 ọdún márùn-ún 33. Jímẹ́kùn 1881-1889 3.5 DÍẸ̀ NÍNÚ ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ỌBA ÌLÚ ÒǸDÓ Ní ilẹ̀ Yorùbá ní ayé àtijọ́, tí wọn ba tí bí ìbejì, wọn a pa wọ́n nítorí abàmì ọmọ ní wọ́n kàásí, lásìkò yìí ni wọ́n bí Òsárewá-sakin ọmọ ọba Olááso ni aláàfin Ọ̀yọ́, ó sí ni ìyàwó púpọ̀. Ó fẹ́ràn ìyá àwọn ọmọ wọ̀nyí kò sí fẹ́ pa wọ́n. Ó kó àwọn ìbejì náà pẹ̀lú ìyá ránsẹ́ sí Epinni ni ìlú àwọn Ìbàrìbá. Nígbà tí ọba Oluaso tẹ̀rí gbaṣo ní 1477, ọba Onígbogí jẹ́ tẹ́lẹ̀. Onígbogí jẹ́ obìnrin tí o jẹ́ ọba ni 1498, kò fé kí wọn fi ìyá jẹ wọ́n, ó sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ ìjà kí ó kọ wọ́n kúrò ní ìlú gba ọ̀nà Ilé-Ìfẹ́, Ìjẹ̀bú ọba Ọọ̀ni sí tún ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lò tẹ̀lé wọn títí wọ́n fi de ìlú Ẹ̀pẹ́. Láti ìlú Ẹ̀pẹ́ ni wọ́n tí rin ìrìnàjò wọn dé ibi ìdí-èdó pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọmọ náà, tó túmọ̀ sí Ese-Omore títí o fi di Òṣemàwé tí ìdí-èdó sí da Òǹdó. Ọba pùpùpù 1510-1530 Gẹ́gẹ́ bi a tí gbọ́ nínú ìtàn pé ìjọba rẹ̀ dára. Ó fẹ́ràn àwọn ohun ọ̀sin púpọ̀ gẹ́gẹ́ bi a tí gbọ pé àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ jọ ń ṣe ìpàdé pọ̀, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ mójútó àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀. Irú ìwà yi bí wọn nínú, tí wọ́n sí pinnu wí pé àwọn kò ní fi obìnrin jẹ ọba mọ́ ni ìlú Òǹdó. Ọba Airo 1530 – 1561 Lẹ́yìn ikú ọba Pupupu ni ọba Airo tẹ̀lé ìyá rẹ̀. ó sí kéré nígbà tí ó jẹ́ ọba, ṣùgbọ́n Àyàdì lọ ń tọ sọ́nà, ó sí ń ba ṣe ìjọba rẹ̀, títí tí o fi le ṣe ìjọba fún ra rẹ̀. Ó dá ẹgbẹ́ Àyàdì àti ẹgbẹ́ òrúnbátó sílẹ̀, ní ọjọ́ kan ó ṣe ìpèdè pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀. ó bẹ̀rẹ̀ sí pààrọ̀ oyè wọn. Ó mú Lísà ṣáájú Jomu, ó mú ọ̀dunwò ṣáájú sàseré. Ó pààrọ gbogbo wọn ó mú ẹni tí ó ṣáájú lọ sí ẹ̀yìn. Nítorí ìwà yìí ni àwọn ìgbàanì ṣe ń pè ní “Airo” ìjọba rẹ̀ sí dára. Ọba Lújù 1561 – 1590 Nígbà tí ọba Airo tẹ́rí gbaṣọ ni ọba Lújù bọ sí orí ìtẹ́, kò tó di ìgbà tó jẹ ọba ni àwọn baálẹ̀. Yorùbá máa ń lọ bá ọba Ọ̀yọ́ ṣe ọdún tàbí kí wọn rán àwọn oníṣe wọn lọ pẹ̀lú ẹ̀bùn. Kété tí ọba Lújù gún orí oyè ní ó lọ farahàn aláàfin ní Ọ̀yọ́. Nígbà tí ó wà ní Ọ̀yọ́, o fi ojú sí bí ọba Aláàfin tí ṣe kọ́ ààfin rẹ̀. Ọba ají bóyèdé ló wà lórí ìtẹ́. Bí Lújù ṣe tí Ọ̀yọ́ dé, ó sọ fún àwọn ará ìlú Òǹdó kí wọ́n kò irú ilé yìí. Ogun bẹ́ sílẹ̀ ni ìlú Òǹdó tí o sí ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun jẹ́ kò sí àlàáfíà. Ìjà yìí pọ̀ tó jẹ́ pé wọ́n kó lára àwọn Òǹdó lẹ́rú; wọ́n sí ṣẹ́gun àsìkò yìí ni Jomu-ńlá yọ sí wọn ó pa púpọ̀ nínú wọn. Lẹ́yìn ogun yìí ni ọba Lújù ṣe oògùn fún Òǹdó pé ogun kò ni jà Òǹdó mọ láéláé. Ó sí rí igi ẹ̀gún káàkiri ìlú, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe kọ́ ilé sẹ́yin igi yìí. Àwọn Òǹdó kò sí kọ́ ilé sí ẹ̀yìn odi ìlú nígbà náà. Ọlọ́run sì gbà bẹ́ẹ̀ fún ọba yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló ṣẹlẹ̀ lásìkò ọba Lújù, àwọn ọmọ rẹ̀ ni òkúta, Lúyàré, Fòyì àti Lẹ́yò. Ọba Lúyàrè 1614 - 1630 Kò sí ogun tàbí ọ̀tẹ̀ lásìkò tirẹ̀ ọmọ Lújù sí ni. Ó sí jẹ́ kí àwọn Òǹdó máa pe ọmọ ìyá kán náà ni gbogbo wọn ó ń ba àwọn Òǹdó kẹ́dùn tí ọfọ̀ bá ṣẹ̀ wọ́n ó sí ní àánú púpọ̀ fún ara ìlú rẹ̀ orúkọ rẹ̀ sí gbilẹ̀ lásìkò tirẹ̀. Ọba Fayi 1630 – 1649 Ọba alákínkanjú ló jẹ́, ó sí jẹ́ ọmọ ọba lúyàré, kí ọba yìí tó jẹ ni àwọn ara ìlú Àmọ̀ná díde ọ̀tẹ̀, tí wọn sí ba ìlú jẹ́, ṣùgbọ́n ó dìde bí akọni ó jẹ́ dódun tí ó bá de ojú ìjà, a mú kí òòyì máa kọ àwọn ọ̀tá rẹ̀ lójú títí o fi gba àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ ìdí tí wọ́n ṣe ń pé ni ọba Fóyì ni èyí. Ọba Lẹ́yọ̀ 1649 – 1668 Ọba Lẹ́yọ̀ ni o jẹ ọmọkùnrin tí ó kéré jùlọ nínú ọmọ ọba Lújù, ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ó sí jé ọ̀rẹ́ sí ọba Ayíbí (ọba Aláàfin Ọ̀yọ́) ṣe ọ̀rọ̀ ìmùlẹ̀. Nígbàkúùgbà ní ọba yìí ń fi àwọn ọmọ ògún ránṣẹ́ sí í, ó sì máa ń ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ọba Gbàjì 1668-1685 Ọba gbàjì jẹ́ ọmọ ọba òkúta, ó kéré nígbà tí ó jẹ́ ọba kò sì olùdádàmọ̀ràn kan fún kò sí gbọ́n púpọ̀, Òǹdó sí rẹ́ ẹ jẹ́. Irú ìwà játi jàti yìí ló mú kí ó máa hu ìwà àíbìkítà sí àwọn Òǹdó, kí o tó wá di pé gbogbo rẹ̀ rọlẹ̀ díẹ̀. Ọba Liyen 1685 – 1701 Ó jẹ́ ọmọ ọba lújù ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ìjẹ̀bú, olóògùn ni ọba yìí. oríṣìíríṣìí egbògi lò wà lọ́wọ́ rẹ̀ kí o tó wá jẹ ọba. Òǹdó sí fẹ́ràn rẹ̀ ó ma ń ṣe oògùn fún aláboyún, ọmọdé àti àgbà. Kí o tó kúrò ni Ìjẹ̀bú, ó mú òrìṣà Ifá àti agẹmọ wá sí Òǹdó lẹ́yìn ìgbà tí ọba yìí tẹ́rí gbaṣọ, àwọn ènìyàn fẹ́ràn láti jẹ́ kí ọmọbìnrin kan ṣoṣo tí o ni di òṣémàwé, nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ni sí ọba yìí, ṣùgbọ́n àwọn Òǹdó tí ṣe ìbúra pé obìnrin kò jẹ ọba ní ìlú Òǹdó mọ́. ORÍ KẸ́RIN FÍFI TÍỌ́RÌ ÌBÁGBÉPỌ̀ ÀWÙJỌ ṢÈTÚPALẸ̀ ÀWỌN ORÍKÌ ORÍLẸ̀ ÒNDÓ 4.0 ÌFÁÀRÀ Oríkì ṣe pàtàkì láàárin àwọn Yorùbá ó máa ń tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn nǹkan tí kí bá fi ara sin nípa ẹni tí ó ni oríkì. Oríkì jẹ́ ewì gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Oyèrìndé (1934:6) tí ó sọ pé Aristotle sọ pé ewì alohùn jẹ́ òtítọ́ ju ìtàn lọ. Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé, ó sàn kí a ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn oríkì àwọn ọba ìlú Òndó kí a ba le rí kókó kan dì mú nípa àwọn ọba wọ̀nyí. Àwọn nǹkan tí ó ṣe pàtàkì tí a lè rí nínú oríkì àwọn ọba ìlú Òndó ni ètò ọrọ̀-ajé, ìbágbépọ̀ àwùjọ. Bákan náà ni a tún rí àwọn kókó mìíràn bí ìfaradà wọn, agbára wọn, iṣẹ́ wọn, ọgbọ́n wọn, ìtàn wọn àti ìwà wọn. 4.1 ÀGBÉYẸ̀WÒ IPA ÀTI IPÒ ÀWỌN ỌBA NÍ ÌLÚ ÒNDÓ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ ènìyàn lásán kò le jẹ́ ọba ní ìlú Òndó bí kò ṣe akọni ènìyàn. A lè mọ ipa àwọn ọba wọn nípasẹ̀ ìwà akin wọn àti agbára tí wọ́n ní pẹ̀lú. Tí a bá wo ẹni tí ń jẹ ọba ní ìlú Òndó, a máa rí i pé, olórí ogun ni. Èyí fihàn pé a lè mọ ipa àwọn ọba nípasẹ̀ ipò wọn. Díẹ̀ nínú àwọn tó jẹ ọba: OYÈ IPÒ Olóyè Àyàdí Ijámà Olóyè Òrúnbátó Lótù ìjámà Olóyè Légírí Líyé majà Olóyè Àrùwá Láogo Ijámà Olóyè Lódàsá Itáwuyì Ijámà Olóyè Lóyìnmi Lójòjò Ijámà Olóyè Sòkòtí Lotogbe Ijámà Báyìí ni ipò àwọn olóyè tí ó jẹ́ ọba ní ìlú Òǹdó. Àwọn ipò yìí jẹ́ pàtàkì ó sì tún jẹ́ ipò fún àwọn alágbára pẹ̀lú. Ipò àwọn ọba yìí kì í ṣe nǹkan tí a lè fojú tẹ́ńbẹ́lú tí ìlú bá ń dára, ó kù sí ọwọ́ ọba tí eku kò bá ké bí eku mọ́, tí ẹyẹ bá ń ké bí ẹyẹ kò ba sì ké bí ẹyẹ mọ́, ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí ọba ni olùdarí ìlú. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀, ọba ni olórí ohun gbogbo, ipa ọba ni láti pàṣẹ fún ìlú tí àṣẹ náà sì gbọdọ̀ múlẹ̀. Ipa àwọn ọba Òǹdó ni pípa àṣẹ gẹ́gẹ́ bí ipò tí wọ́n wà. Lára àwọn ipa ọba ìlú ni láti to ìlú wọn. wọ́n a máa to ìlú kí rúdurùdu má ba à le wáyé èyí sì jẹ́ pàtàkì lára ipa àwọn ọba yìí kí alaafia le bá a jọba ní ìlú Òndó. Bákan náà ni a tún rí àwọn Ìwàrẹ̀fà tí ó ní ipa tí ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ń kó ní ìlú Òǹdó, kí ìjọba ó lè rọrùn ní ṣíṣe, wọ́n máa ń yan àwọn ìjòyè láàárín ìlú sí àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan tí ìbáṣẹpọ̀ wọn sì máa ń dánmọ́rán. Bí àpẹẹrẹ OYÈ IPÒ Olóyè Òrúntó wà fún Òkèlísà Olóyè Arógbó òkè odunwo Olóyè Lógbòsẹ́rẹ́ ọ̀rérétu Olóyè Sàsọ̀rẹ odòsídà Olóyè Jomu Lẹ́gírí ìdí Lẹ́gírí Bákan náà ni a tún rí àwọn ìgbìmọ̀ olùdámọ̀ràn ọba tí ó j ewì pé ojúṣe wọn ni yíyan ọba sí ipò. Ó ní àwọn ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé ní yíyan ọba sí ipò ní ìlú Oǹdó. Lára àwọn olóyè ni ó máa ń kópa nínú àwọn ètùtù ìfijoyè. Ìlànà tí wọ́n máa ń lò nìwọ̀nyí 4.1.0 Ì GBÉSẸ̀ ÌFINIJOYÈ ỌBA ÌLÚ ÒNDÓ ÌGBÉSẸ̀ KÌÍNÍ: Àwọn olùránṣẹ́ tí a ń pè ní òdìbò, Lísà, Jomu, òdunwò sàsọrẹ́ àti Adájà ni yóò sin àwọn olóyè àti ṣamọ̀rà lọ sí abúlé láti lọ mú òṣèmàwé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn. Wọn yóò sọ fún un wí pé, wọ́n wá láti wá mu nítorí ìbáṣẹpọ̀ tí ó ní pẹ̀lú ìyàwó olóyè gíga Lísà. Lẹ́yìn tí òṣemàwe tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn bá ti tako ẹ̀sùn yìí ni wọn yóò sọ fún pé àwọn ará ìlú Òǹdó ni ó fẹ́ kí ó jẹ òṣemàwe ti ìlú Òǹdó, yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì ta wọ́n lọ́rẹ ewúrẹ́ kan. ÌGBÉSẸ̀ KEJÌ Olóyè Lísà sàsọrẹ́ yóò mú òṣèmawé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn lọ sí ilé olóyè Lísà ni òkèlísà ní àdúgbò lákó ní nǹkan bí déédé agogo márùn-ún àárọ̀ ọjọ́ kejì tí ó bá dé ilé rẹ̀. Níbẹ̀ ni àwọn Ìwàrẹ̀fà yóò ti ṣe ayẹyẹ ìkọlà ojú fún òṣemàwé. Egbò ilà yìí gbọdọ̀ san láàárín ọjọ́ méje tí ó jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ rí wọn lásìkò náà. Lẹ́yìn ọjọ́ méje oṣù mẹ́ta wọ́n ní láti parí gbogbo ètò yìí gbogbo àwọn olóyè ni wọ́n yóò ránṣẹ́ sí láti wá kó ipa tí ó tọ́ sí ẹnìkọ̀ọ̀kan láti kó nínú ètò ìfijoyè yìí. ÌGBÉSẸ̀ KẸ́TA Nígbà tí ó bá ku ọjọ́ méjì tí àwọn ayẹyẹ wọ̀nyí yóò bẹ̀rẹ̀ àwọn olùbọ olóyè márùn-ún tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ekìrì, Ọbalúfọ̀n, Súmọ́ Sàò sanyìn àti ọlọ́jà dókò ni yóò lọ sí ilé olóyè gíga Sàsọré láti mú Òṣemàwé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn lọ sí ojúbọ tí ó wà ní ọ̀nà Èpè fún ètùtù, kí wọ́n tó kúrò náà yóò ti ta aṣọ funfun mọ́ lọ́rùn. Nígbà náà ni wọn yóò mu lọ tààrà sí ilé ọlọ́jà-Dókò tí wọ́n bá ti dé ìlú. Lẹ́nu ibodè tí ó kángun níbi tí ọlọ́jà-Dókò tí ń dúró dè wọ́n ni yóò ti bọ aṣọ funfun ọrùn Òṣémàwe tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn. Lẹ́yìn èyí ni wọ́n yóò kẹ̀yìn sí ara wọn. èyí tí ó fi hàn pé Òṣemàwé tuntun yìí kò gbọdọ̀ gbá ilé ọlọ́jà Dókò mọ́. Àwọn olùbọ olóyè yìí yóò máa mú Òṣemáwe padà lọ sí ilé olóyè gíga Sàsọré. 4.2 IPA ÀTI IPÒ ÌLÚ ÒNDÓ NÍPA OGUN JÍJÀ Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ipa àti ipò Òǹdó nípa ogun jíjà, Òǹdó kì í ṣe nǹkan tí a lè fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ogun jíjà. Ogun jíjà ni ó sọ Òǹdó di ìlú tí ipò rẹ̀ ga ní àwùjọ Yorùbá lónìí yìí. Bákan náà, tí a bá wo ọba pùpùpù tí ó tẹ ìlú Òǹdó dó, alágbára ni jagunjagun sì ni pẹ̀lú. Agbára, akínkanjú tí àwọn jagunjagun Òǹdó jẹ́ kì í jẹ́ kí àwọn ara àdúgbò wọn le è kọ iyán wọn kéré. Wọ́n máa ń fi Òǹdó sí ipò ńlá nípa èyí. Ènìyàn kò le è ni ipò tó ní láárí ní ìlú Òǹdó bí kò bá jẹ́ akọni. Akọni ni ó ń di ipò mú ní ìlú Òǹdó. Wọ́n sì máa ń yàn wọ́n sípò nípa ipa tí wọ́n ti kó sẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ ọba Bàjùmù tí ó jẹ́ alákínkanjú bí bàbá rẹ̀, ó lọ sígun bá ìlú kan tí ó súnmọ́ Òǹdó nígbà tí ó gbọ́ pé wọ́n fẹ́ máa jẹ gàbalé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí. 4.2.1 IPA ÀTI IPÒ ÀWỌN ỌBA ÌLÚ ÒNDÓ GẸ́GẸ́ BÍ ALÁGBÁRA Àwọn ọba ìlú Òǹdó jẹ́ olórí ogun. Wọ́n lágbára wọ́n sì jẹ jáde nínú oríkì wọn. Oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí wọ́n gbà fi agbára hàn ló wà nínú oríkì wọn. Àpẹẹrẹ èyí jẹ jáde nínú oríkì ọba òkúta Òyán onídà Òyanyàn nímú Ògbogbò létí Ó ṣe owó ọba onídà Egún ńlá o. (ilà 1-5) Gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú oríkì wọn a tún rí àpẹẹrẹ agbára oògùn tí ó jẹyọ nínú oríkì ọba Lósùnlá (1893-1909) Ajagíjigì oògùn Orìṣà Ẹ̀gbá kúkú Olókè mẹ́ta Ó sọmọ di pùyépùyé (ilà 2-8) Yàtọ̀ sí agbára oògùn tí àwọn ọba wọ̀nyí ń lò, wọ́n kápá àwọn ènìyàn dáadáa, wọn a sì máa lo agbára àti ipò wọn lórí àwọn ènìyàn wọn. Àpẹẹrẹ èyí hàn nínú oríkì Jomu (1909-1917) Ó pa baba wọn run Ó pa ayé run Ó pa onígbọ̀wọ́ Ó dá jẹ ẹran míní-míní Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú òkè yìí, Jomu tí ó ni oríkì yìí náà le ní ẹ̀dá. Bákan náà agbára wọn pọ̀ dé ibì kan dé ibi pé wọn a máa fi ìyà jẹ ìjòyè ìlú wọn kò sì bẹ̀rù àjẹ́ nítorí wọ́n ní agbára. 4.2.2 OGUN JÍJÀ Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀rí tí a ti rí fàyọ nínú oríkì àwọn ọba yìí a tún rí ẹ̀rí mìíràn tó tún fúnka mọ́ ọn pé yàtọ̀ sí pé wọn lówó, wọ́n lọ́lá, wọ́n nípò, wọ́n ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti rí i pé ogun kò ja àwọn ènìyàn wọn. Wọ́n ní agbára láti jagun ṣẹ́gun. Àpẹẹrẹ èyí ni a rí nínú oríkì ọba Àfaidùnjoyè (1876-1881) àsìkò ọba yìí ni wọ́n lọ ṣígun bá Ìrelé ní ìgbà kejì “ọmọ ọba Arógun má tìdí Àjànàkú sọwọ́ ìjà sókè Ọmọ aródẹ́dẹ́ wọnú ogun Ọmọ afẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́jẹ̀ wẹ̀. 4.2.3 IṢẸ́ ÒÒJỌ́ WỌN Yàtọ̀ sí pé wọ́n máa ń ta kókó, wọn kì í fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú iṣẹ́ àgbẹ̀ ní ṣíṣe ní ìdílé wọn. Wọ́n a sì máa ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú oko wọn, àti pé iṣẹ́ àgbẹ̀ yìí sì máa ń sọ wọn di olówó púpọ̀. “oroko-roko gbọwọ́ ọ fújà Kì í sọmọ ìbílẹ̀ lo ṣe lọ Ó mókó nílé Ó mú àdá nílé Ó dágbádá wọnú oko Bákan náà ojúlówó iṣẹ́ wọn, àwọn ọba ìlú Òndó ní láti dábò bo àwọn ara ìlú. Àpẹẹrẹ èyí wa nínú oríkì ọba Àpèrúwà 1926-1935 Ará ìjámá Ó sékẹ̀ ará ìlú Ó sèké Àlejò Àlejò gbàgbé ilé 4.2.4 ÈTÒ ÌṢÈLÚ Onírúurú ọ̀nà ni àwọn Òndó ń gbà ṣe ètò òṣèlú wọn. Wọ́n ń ṣe àwọn nǹkan yìí kí ìlú ba à lè tùbà tùṣẹ. A lè rí lára ọ̀nà òṣèlú wọn. Ọba Ìbídàpọ̀ Adédìísẹwo Adésànájè 1992-2000 ní kété tí ọba yìí gorí oyè, ó ṣe àbẹ̀wò sí gbogbo agbègbè tí ó wà ní Òǹdó láti rí i pé ìfẹ́ àti àlàáfíà wà. Ó rí i pé ìlú Òǹdó ń gbé ayé ìrọ̀rùn, ó dá agbègbè márùndínlógún mìíràn sílẹ̀ (Ijámà). Ọba yìí jẹ́ onígbàgbọ́ tí ó sin Ọlọ́run bí ó ti yẹ. Àsìkò rẹ̀ ni wọn dá ìjọba Òǹdó sí méjì (ìlà Oòrùn) àsìkò yìí ni wọ́n gbìmọ̀ láti sọ ilé ẹ̀kọ́ gbogbońṣe di Fásitì. Olówó ni ọba Adésanoyè kí ó tó jẹ́ ọba ìlú Òǹdó, olówó jaburata ni. Ó kọ́ ààfin ìgbàlódé fún àwọn ará ìlú. Òun ni ọba kejì tí ó lọ sí ilẹ̀-ọba (Òkè-Òkun) Ní kété tí ó dádé lẹ́yìn ọdún mẹ́ta ni ọmọ bíbí ìlú Òǹdó di Gómìnà ìpínlẹ̀ náà. Òun ni Dókítà ọmọ bíbí ìlú Òǹdó tí ó jọba, ó sì tún máa fún àwọn aláìní lówó, ó sì tún fi owó rẹ̀ kọ́ ilé Ọlọ́run àti mọ́sálásí, ó gbìyànjú nígbà ayé rẹ̀. Ọba yìí ṣe ohun máànígbàgbé sí Òǹdó, ó fẹ́ràn ijó àti orin ìgbàgbọ́ púpọ̀. Ọba yìí kò gbà kí wọ́n fi owó du oyè mọ́. Ìgbà ọba yìí ni wọ́n kọ́ ọjà tuntun tí ó wà ní sábó. Ó ṣe gudugudu méje àti yàyà mẹfà fún ètò àti ìlọsíwájú ìlú Òǹdó. 4.3 Ìmúra Bákan náà a máa rí i pé ìmúra wọn jẹyọ nínú oríkì wọn Ọmọ àfẹ́rí wọ̀wọ̀ sọrọ̀ Aji ṣówó otùn ọwọ́ Ekejì ìlẹ̀kẹ̀ Ọmọ Aládé igbó Òjiwà jiwa ìlẹ̀kẹ̀ Bákan náà, ní ìlú Òǹdó ìmúra wọn máa ń yàtọ̀ sí ara wọn. Ìdí èyí ni wí pé, àwọn ará ìlú yìí yóò tètè mọ̀ iru ẹgbẹ́ tí wọn wà. Èyí ni à ń pè ní ìpelè, ṣùgbọ́n lóde òní, olóyè àti ẹni tí kò jẹ oyè máa ń múra láì mọ̀ ìtumọ̀ wọn. Èkíní: Àwọn òtú máa ń fi tiwọn kọ́ ọrùn, ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì yìí yóò kọjá àyà. Èkejì: Àwọn ọ̀túnba wọ́n a fi aṣọ tiwọn kọ́ ọrùn ọwọ́ rẹ̀ yóò sì lọ sí ẹ̀yìn. Bákan náà ni a tún rí àkún ọwọ́ àti ti ẹsẹ̀ tí ó wà fún ọba pẹ̀lú àwọn Ìwàrẹ̀fà nìkan, ṣùgbọ́n àwọn olóyè tó kù le wọ àkún sí ọwọ́ kan ṣoṣo. Gẹ́gẹ́ bí òwe ilẹ̀ Yorùbá pé ọba ló ladé orí, ìlẹ̀kẹ̀ ni ti àwọn ìjòyè. Ní ìlú Òǹdó àwọn olóyè máa ń fi àkún sọ́wọ́ méjèèjì ṣùgbọ́n àwọn òpójí le fi sí ẹsẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ méjèèjì. Ẹni tí kò bá jẹ oyè kò gbọdọ̀ fi àkún sí ọrùn tàbí ọwọ́. Bákan náà, ẹni tí kò ní ìyàwó kò gbọdọ̀ jẹ oyè. Gbogbo àwọn kókó tí a rí fàyọ yìí ni ó ṣe pàtàkì nínú oríkì orílẹ̀ àwọn ọba ìlú Òǹdó. ORÍ KARÙN-ÚN ÀBÁLỌBÁBỌ̀ 5.0 ÌFÁÀRÀ Bí ọkọ bá ròkun rọ̀ṣà èbúté ni yóò gúnlẹ̀ sí. Orí tí ó gbẹ́yìn iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ni a dé báyìí. Gbogbo ìlàkàkà wa lórí iṣẹ́ yìí àti àríwòye tí a ni tí ó jẹyọ ni yóò jẹ́ pàtó orí yìí. A ó ṣe ìsọníṣókí àbájáde ìwádìí, àmúyẹ, àléébù àti ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú. 5.1 ÌSỌNÍṢÓKÍ ÀBỌ́ ÌWÁDÌÍ Láti ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ni ó ti farahàn pé ipa àti ipò pàtàkì ni oríkì ń kó láwùjọ àwa ọmọ Yorùbá. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ṣe jẹ́ ìjánú ọmọ ni oríkì jẹ́ ìtọsẹ ọmọ ènìyàn. Ìlú Òǹdó ti ó jẹ́ ọ̀kan lára ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ Òǹdó ni ó jẹ́ kókó àpilẹ̀kọ yìí. Ọ̀pọ́ òye àti ìmọ̀ ni àpilẹ̀kọ yìí sì ti tún mú jáde nípa ìlú Òǹdó àti oríkì ọba wọn. Lára àwọn ọgbọ́n àti ìmọ̀ tí a rí fàyọ nínú àpilẹ̀kọ yìí ni pé bí oríkì ṣe pàtàkì láàárín ìran Yorùbá, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe pàtàkì ní ìlú Òǹdó. Èyí farahàn láti ara oríṣìí àwọn oríkì àdání àti oríkì àwọn ọba tí a bá pàdé nínú àpilẹ̀kọ yìí. Lára àwọn ohun tí a bá pàdé nípa oríkì àwọn ọba yìí náà ni pé ó jẹ́ kí a mọ̀ wọn bí alágbára àti alákínkanjú ènìyàn. Bákan náà, ó tún ń ṣe àfihàn àwọn àṣà tí wọ́n gùn lé nípa pé wọn máa ń ní àánú àwọn ènìyàn lójú púpọ̀. A kò ṣàì rí ipò wọn nínú oríkì a rí i pé ìṣèlú wọn tó jẹyọ nínú oríkì wọn yìí náà ni pé, wọ́n máa ń jẹ oyè mìíràn yàtọ̀ sí ọba. Àfihàn oríkì àdáni tún jẹyọ nínú oríkì àwọn ọba wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá ṣe ní oríkì àdáni. Yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́, àṣà yàtọ̀ sí èyí tí a ti mẹ́nu bà lókè ni ó tún jẹyọ nínú oríkì àwọn ọba wọ̀nyí tí a bá pàdé. 5.2 ÀMÚYẸ ÀTI ÀLÉÉBÙ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Pàtàkì ohun tí ó jẹ́ àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí yìí ni pé, ó gbé àṣà àti ìṣe Yorùbá yọ. Ó sì tún mú kí àwọn ohun tí ó ti ń dohun ìgbàgbé tún di àmúlò padà nílẹ̀ Yorùbá lápapọ̀ àti pàápàá ìlú Òǹdó, bí àpẹẹrẹ a kì í ki oríkì mọ́ níbikíbi yálà níbi ayẹyẹ kan ni tàbí nínú ilé láti ṣe kóríyá fún ènìyàn. Lọ́nà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ó mu kí a ní ìmọ̀ àmọ̀dájú nípa ìlú Òǹdó tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìlú Òǹdó. À mọ àṣà, ìṣe, èèwọ̀, iṣẹ́ àwọn baba-ńlá wọn àti oríkì àwọn ọba wọn. yàtọ̀ sí èyí a tún ní àǹfààní láti ní òye àti ìmọ̀ tó dájú nípa ètò òṣèlú àti ìṣèjọba lápapọ̀ àti pàápàá ètò ẹ̀sìn àti ètò wọn láti ibi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ àti ibi tí ó gbòòrò dé báyìí lónìí. Láì ṣe àníàní, bí a ṣe rí àmúyẹ nípa iṣẹ́ yìí náà ni a rí àléébù rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn àléébù náà ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn ni kò fi taratara dáhùn sí àwọn ìbéèrè tí a ń béèrè lọ́wọ́ wọn. Bákan náà àwọn mìíràn rò pé ń ṣe ni a wá láti jí àwọn ohun ìṣúra wọn kó lọ, nítorí ìdí èyí, onírúurú wàhálà, ìdààmú àti àbùkù ni wọ́n fi kàn wà kí á tó lè rí ìwádìí díẹ̀ ṣe fún iṣẹ́ ìwádìí yìí. 5.3 ÌMỌ̀RÀN FÚN IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Ohun tó dájú ni pé ọgbọ́n kò pin sí ibì kan. Ibi tí ènìyàn bá ṣe é dé ni ó ń rí i mọ. Ibi tí ènìyàn bá sì rí i mọ ni yóò sọ̀rọ̀ dé. Ibi tí aṣèwádìí yìí bá a dé ni ṣíṣe àlàyé lórí oríkì àwọn ọba ìlú Òǹdó, ṣùgbọ́n òye tí a tún ní ni pé ìwádìí lè dá lé ewì àbáláyé mìíràn bí i bọ̀lọ̀jọ́, àrùngbè tí ó lè fi kún ìmọ̀ wa nípa ìlú Òǹdó. Yàtọ̀ sí èyí, ààyè ìwádìí sì tún wá lórí oríkì àdáni àwọn ìdílé mìíràn tí wọ́n jẹ́ ìdílé olóyè yàtọ̀ sí ìdílé ọba ní ìlú Òǹdó. 5.4 ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ Láìṣe àní-àní, a ti ná ìgbárá a ti ná ìgboro lórí iṣẹ́ ìwádìí yìí. ibi tí a bá dé rè é lórí àgbéyẹ̀wò oríkì àwọn ọba ìlú Òǹdó. Ṣáká ló dájú bí àdá pé nínú oríkì àwọn ọba ìlú Òǹdó ni a ti rí gbogbo ohun tí àwọn ọba náà àti àwọn baba-ńlá wọn ti gbé ṣe. Kò sí júu jùu tí ẹnikẹ́ni fi lè boni lójú tí a bá ka oríkì wọn. akínkanjú, alágbára ni àwọn ọba tí ó ti jẹ ní ìlú Òǹdó. ÀKÓJỌ ORÚKỌ ÌWÉ Adéoyè, C. (1969), Orúkọ Yorùbá. Ìbàdàn: The Caxton Press (West Africa) Limited. Adéoyè, C. (1978), Àṣà àti Ìṣe Yorùbá. London: Oxford University Press. Adéyẹmí, L. (2006:8), Tíọ́rì Lítíréṣọ̀ Ní Èdè Yorùbá. Ìjẹ̀bú Òde: Shebiotimọ Publications Akinbinuade, A. (2009), Oríkì àti Ètò Ayé Ìlú Òǹdó P.O Box 556. Babalọlá, A. (1966). The Content and Form of Ìjálá. Ìbàdàn: Oxford University Press. Babalọlá, A. (1973), Orin Ọdẹ fún Àṣeyẹ. Lagos:Macmillan Nigeria Industrial Estate. Babalọlá, A. (2000), Àwọn Oríkì Orílẹ̀ Mẹ́tàdínlógún. Lagos: Longman Nigeria PLC Babalọlá, A. (1975), Àwọn Oríkì Bọ̀rọ̀kìnní. Lagos: Longman Nigeria PLC Dáramọ́lá, O. àti Jẹ́jẹ́, A. (1975). Àwọn Àṣà àti Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá. Ìbàdàn: Oníbọnòjé Press. Ládélé, T. àti Fáníyì, J.O.O (1979), Ẹkún Ìyàwó. Ìbàdàn: Longman Nigeria Limited. Ògúnbọ̀wálé, P.O (1966), Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá. Ìbàdàn: University Press Limited. Ọlábímtán, A. (1986:197). Àkójọpọ̀ Ìwádìí Ìjìnlẹ̀ Àṣà Yorùbá Àṣà Yorùbá. Ìbàdàn: Gavima Press Limited. Ọlátúnjí, O. (1984:67-105), Features of the Yorùbá Oral Poetry. Ìbàdàn: University Press Limited. Ògúnṣínà, B. (2006), Sociology of the Yorùbá Novel: An Introduction. Integrity: Taiwo Road Ìlọrin Kwara State Nigeria, Publication Ṣówándé, F. àti Fágbèmí, A. (1969), Orúkọ Àmútọ̀runwá. Ìbàdàn: Oxford University Press. Yémiítàn, O. (1982:1), Ìjálá Aré Ọdẹ. Ìbàdàn: University Press Limited. ORÍKÌ ORÍLẸ̀ Oǹdó NÍ ÌLÀNÀ dàńsáákì sábó ọfọ̀ jímosùn òkèlísà àníàní òfútùfẹ́tẹ̀ lọ́kanòjọ̀kan òṣemàwé àti lísà ìlú oǹdó ẹ̀dáèdè tìdí òpómúléró adésanoyè ọlábímtán ṣètúpalẹ̀ abímbọ́lá gbogboǹṣe ADÉDÈJÌ ADÉNÍKẸ̀Ẹ́ TÓSÌN APÁ KAN IṢẸ́ ÀṢEKÁGBÁ FÚN Ẹ̀KỌ́ ÀKÀGBOYÈ NÍNÚ ÌMỌ̀ ÌPÌLẸ̀ Ẹ̀DÁ NÍNÚ ÈDÈ YORÙBÁ NÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ YUNIFÁSÍTÌ ÌLỌRIN ÌLỌRIN NÀÌJÍRÍÀ OṢÙ ÈBÌBÌ ỌDÚN ÌFỌWỌ́SÍ Iṣẹ́ àkànṣe yìí ni a ti kà tí a sì rí i pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Èdè Nàìjíríà Yunifásítì Ìlọrin Ìlọrin ALÀGBÀ ÒKÉWÁNDÉ ỌJỌ́ ALÁBÒÓJÚTÓ OLÙYẸ̀WÒ ÌTA ỌJỌ́ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N ỌJỌ́ OLÓRÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁ ÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ÌFISỌRÍ Mo fi ìwé yìí sọrí ọba àwọn ọba Àìkú Àìsá Atẹ́rẹrẹ káríayé ògbìgbà tí í gba aláìlárá Ẹlẹ́rù níyìn ọba tó ń gba aláìlẹ́ni kan ajípọjọ́ikúdà yaágbóyaájù ọkùnrin ogun Ajagungbadé ọba ìyanu ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin fún dídà tí ó da mi sí dọjọ́ òní Àti Àwọn òbí mi ọ̀gbẹ́ni àti ìyáàfin Adédèjì fún akitiyan wọn lórí mi láti le jẹ́ kí ń jẹ́ ènìyàn láyé Ẹ ṣeun ÌDÚPẸ́ Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọba Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run awímáyẹhùn òwí bẹ́ẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ Ẹ́kùn ọkọ Fáráò Adúró gbọin gbọin lẹ́yìn aṣòótọ́ Òun ni o rànmọ níṣẹ́ fàyà tì í Ọba tó fún mi ni àṣeyọrí tó lógo nínú ẹ̀kọ́ Òun ló tún mú kí iṣẹ́ ìwádìí mi gúnlẹ̀ láyọ̀ Bákan náà mo dúpẹ́ lọ́wọ́ bàbá àti ìyá mi fún àtìlẹ́yìn sùúrù ìjìyà àti ìtọ́jú wọn lórí mi Ẹ ṣeun púpọ̀ oúnjẹ ọmọ á jiná fúnun yín jẹ ní orúkọ Jésù ẹ kò ni ṣe àṣedànù Ẹni ẹlẹ́ni kò sì ni gbà ṣe yín ṣe Ọpẹ́ pàtàkì mi tún lọ sọ́dọ̀ alábójútó iṣẹ́ mi ọ̀gbẹ́ni Okewande Olúwọlé Tẹ́wọ́gboyè fún akitiyan wọn láti mú kí iṣẹ́ ìwádìí mi yìí yọrí sí rere Ẹ ṣeun ẹ kú iṣẹ́ mi Ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀gá mi alàgbà Wàlé Rafiu Alàgbà Ọmọlayọ̀ Ògúnlọlá Alàgbà Ọ̀tún Ọ̀mọ̀wé Adéyẹmí èmi kò ní gbàgbé yín Ẹ ṣeun Ọpẹ́ mi tún lọ sí ọ̀dọ̀ abẹ́nàìmọ̀ mi Akinbinuade Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi gbogbo Aya Ọlánírègún Jọkẹ́ Adédèjì àti Seun Adèdèjì Bákan náà mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn akẹgbẹ́ mi gbogbo; mo sì tún dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n yìí Ọláníran Láídé Akínpẹ̀lú Abímbọ́lá Ajíbóyè Ọmọ́wùnmí Tọ́pẹ́ Ràmọ́nù Abíọ́lá Folúkẹ́ Bùsáyọ̀ àti Abíọ́dún ÀṢAMỌ̀ Nígbà tó jẹ́ wí pé afìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ hàn ni lítíréṣọ̀ kókó ohun tí a gbéyẹ̀wò nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni ewì alohùn Yorùbá láti fa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ yọ Àwùjọ tí iṣẹ́ yìí sì dálé lórí ni àwùjọ ìlú Òndó Nínú iṣẹ́ yìí oríkì àwọn ọba ìlú Òndó ni a gbé yẹ̀wò oríṣìíríṣìí ọgbọ́n ìwádìí ni a sì ṣe àmúlò rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò le ṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ kan bí i ewì láìṣe àmúlò tíọ́rì kan tàbí àtinúdá Tíọ́rì tí a ṣe àmúlò nínú iṣẹ́ yìí ni tíọ́rì Ṣosíọ́lọ́jì lítíréṣọ̀ Bákan náà a ṣe ìgbéléwọn àwọn oríkì ọba ìlú Òndó láti mọ àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí a sì tún fi àwọn oníṣẹ́ akadá tó ń bọ̀ lẹ́yìn ní ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ÀTẸ ÀKÓÓNÚ Àkọlé Ìfọwọ́sí Ìfisọrí Ìdúpẹ́ Àṣamọ̀ Àtẹ Àkóónú ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Ìfáàrà Èrèdí iṣẹ́ ìwádìí Ibi tí ìwádìí gbòròò dé Ọgbọ́n ìwádìí Àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí yìí Ètò ìwádìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN Ìfáàrà Oríkì ní àwùjọ Yorùbá Oríkì orílẹ̀ Ìbáṣepọ̀ láàárín oríkì àti lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá mìíràn Tíọ́rì Tíọ́rì Ìṣàmúlò Tíọ́rì Ìfojúìmọ̀ ìbáraẹnigbépọ̀láwùjọ woiṣẹ́ lítíréṣọ̀ ORÍ KẸ́TA ÀWÙJỌ TÓ BÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌLÚ Oǹdó Ìfáàrà Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Oǹdó Àlàyé lórí oríkì orílẹ̀ Oǹdó Oríkì àwọn Ọba kọ̀ọ̀kan Àwọn ọba tó ti jẹ àti ọdún wọn Díẹ̀ nínú ìtàn ìgbésí ayé àwọn ọba ìlú Oǹdó ORÍ KẸ́RIN FÍFI TÍỌ́RÌ ÌBÁGBÉPỌ̀ ÀWÙJỌ Ṣ`ETÚPA LẸ ÀWỌN ORÍKÌ ORÍLẸ̀ Oǹdó Ìfáàrà Àgbéyẹ̀wò ipa àti ipò àwọn ọba ni ìlú Oǹdó Ìgbésẹ̀ ìfinijoyè Ipa àti ipò Oǹdó nípa ogun jíjà Ipa àti ipò àwọn ọba Òndó gẹ́gẹ́ bí alágbára Ogun jíjà Iṣẹ́ òòjọ́ wọn Ètò ìṣèlú Ìmúra ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ Ìfáàrà Ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí yìí Àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí Ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú Àgbálọgbábọ̀ Àkójọ orúkọ ìwé ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀SẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌFÁÀRÀ Náání nàànì náání ohun a ní làá náání ìran aṣẹ́gità ní í náání èèpo igi ìran ọmọ Yorùbá a sí máa náání àṣà wọn Onírúurú bí aṣọ alágẹmọ a ní àṣà tí ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ mọ èyí a fi ń dánilárayá bì í orin ìtàn àròsọ àti ewì Nínú gbogbo iṣẹ́ ìwádìí yìí ewì ni a yàn láàyò Ẹ̀yà ara ewì alohùn ni oríkì wà oríṣìíríṣìí oríkì sí ni ó sí wà Bí oríkì ìnágijẹ bọ̀rọ̀kìnní àníjẹ́ àdájẹ́ oríkì orílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Bí a ṣe rí oríkì àwọn ohun ti kì í ṣe ènìyàn ṣùgbọ́n tó jẹ́ ohun abẹ̀mí bí i ẹyẹ ẹranko àti àwọn ohun ọ̀gbìn mìíràn Nínú iṣẹ́ yìí oríkì ni a ó máa gbẹ́ yẹ̀wò kì í sí i ṣe oríkì àwọn ènìyàn lásán bí kò ṣe oríkì àwọn ọba oríkì àwọn ọba tí a sí ń wí yìí rinlẹ̀ ni àwọn ìlú ilẹ̀ Yorùbá Ó máa ń fi bí ipò oníkálùkú àwọn ìlú wọ̀nyí ló ní ọ̀nà tí wọn ń gbà gbé oríkì kalẹ̀ Bí àpẹẹrẹ àrà ọ̀tọ̀ ní oríkì ọba ni Ọ̀yọ́ Àwọn apohùn ló máa ń kéwì yìí Bí a ṣe rí ìgbékalẹ̀ oríkì àwọn ọba ìlú Ọ̀yọ́ náà ni ṣe rí ìgbékalẹ̀ oríkì àwọn ọba ìlú Ẹ̀gbá Ìjẹ̀bú Oǹdó láti mọ ètò láti mọ ètò àṣà àti ìṣẹ̀dá àwọn ẹ̀yà yìí ìlú Oǹdó jẹ́ ẹ̀yà Yorùbá ni ijọbá ìwọ̀ oòrùn ní ìpínlẹ̀ Oǹdó ìlú tí wọ́n bá pààlà ní ìlú Ìkálẹ̀ tí òun náà wà ní abẹ́ ijọbá Gúúṣú ìwọ̀ oòrùn ní ìpínlẹ̀ Oǹdó ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Bí kò bá nídìí obìnrin kì í jẹ́ kúmólú Ìdí pàtàkì tí a fi dágbálé iṣẹ́ yìí ni láti ṣàfihàn oríkì gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan pàtàkì nínú ọ̀nà tí a ń gbé àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá ga A wò ó gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan pàtàkì tí a fi ń pa ìtàn ìlú mọ́ Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àṣà tí ó rinlẹ̀ ni ìlú Oǹdó Kò sí ilé àdúgbò ọlọ́danni tàbí olóyè tí ó wà ni ìlú Oǹdó lónìí tí kò ni oríkì kan tí ó ń fi orísun àti ìhùwàsí wọn hàn Àtúpalẹ̀ oríkì yóò fún wá ní àǹfààní láti mọ ibi ti wọn ti ṣè wá iṣẹ́ wọn èèwọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹ̀yà Yorùbá Lọ́nà mìíràn orísun wọn àti ìbátan wọn pẹ̀lú ẹ̀yà àti ìlú mìíràn IBI TÍ ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ Nínú iṣẹ́ yìí a ṣe àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ ọnà àtinúdá bì i ewì ní pàtàkì jùlọ oríkì láwùjọ Yorùbá Iṣẹ́ yìí tan iná wo oríkì tí a le bá pàdé láwùjọ Yorùbá bí i; oríkì orílẹ̀ àti ti ọba Ṣe okùn kì í gùn kò má ni ibi tí a fàá wà Iṣẹ́ yìí tọpinpin orírun ìlú Oǹdó tí a ń gbéyẹ̀wò ìdílé kọ̀ọ̀kan tó ti jẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ títí di òní Síwájú sí i a ó ṣe àtúpalẹ̀ oríkì orílẹ̀ ní ìlànà tíọ́rì ìfojú ìmọ̀ ìbáraẹnigbépọ̀ láwùjọ woiṣẹ́ lítíréṣọ̀ Ní àgbálọgbábọ̀ a ó wo àwọn àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí àti ìmọ̀ràn fún ìlò atọ́ka ọjọ́ iwájú ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ Kí èròǹgbà wa lórí ìfojú tíọ́rì ìmọ̀ìbaraẹnigbépọ̀láwùjọwo oríkì orílẹ̀ le di mímú ṣẹ a gbọdọ̀ ṣe àmúlò ọgbọ́n ìwádìí tó kún tó sí múná dóko ọgbọ́n ìwádìí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti ọgbọ́n ìwádìí líọ sí yàrá ìkówèépamọ́sí Ọgbọ́n ìwádìí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò jẹ́ ọgbọ́n ìwádìí kan tó ṣe pàtàkì Ṣe bí ọmọdé kò bá ìtàn dandan ni kí ó bá àrọ́bá Ẹ̀rọ agbohùn tí a mọ sí téèpù ni a ó lò láti gba ohun òǹkọ̀wé sílẹ̀ kí a tó lọ sí ọ̀dọ̀ abẹ́nàìmọ̀ a tí kọ́kọ́ ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìbéèrè tó múnádóko tí a ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ Ìdí tí a fi lo ẹ̀rọ agbohùn nínú iṣẹ́ yìí ni kí o bà a lé rọrùn fún wa láti rántí ohùn gbogbo tí a bá gbọ́ lẹ́nu abẹ́nàìmọ̀ Síwájú sí i ọgbọ́n ìṣèwádìí mìíràn ni lílọ sí iyàrá ìkówèépamọ́sí Èyí sí fún wa ní àǹfààní láti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí àwọn onímọ̀ ti ṣe lọ́kanójọ̀kan lórí iṣẹ́ tó jẹ́ mọ́ iṣẹ́ yìí A rí àwọn oríṣìíríṣìí ìwé ti àwọn aṣááju tí kọ Gbogbo ìwọ̀nyí ni yóò ran wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò fún wa ní ìmọ̀ tí o gbòòrò nípa iṣẹ́ ọ̀nà àtinúdá Yorùbá ewì ní pàtàkì oríkì Iṣẹ́ ìwádìí yìí wà fún ìgbélárúgẹ àṣà àti iṣẹ́ Yorùbá Ojú abùkù tí àwọn kan fi ń wo ó sì le fi bẹ́ẹ̀ di ohùn ìgbàgbé pátápátá Bákan náà yóò ṣe àfikún ìmọ̀ nínú oríkì àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá tí a ti mọ tẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ sí ni láti mu kí àwọn oríkì wọ̀n yìí wà lákọọ̀lẹ̀ yóò sí tún ran wá lọ́wọ́ láti mọ ipa ipò àti ìtàn ìgbé ayé àwọn ọba tó ti jẹ́ ni ìlú Oǹdó ÈTÒ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Orí márùnún niṣẹ́ yóò pín sí orí kìíní ni a ti ṣàlàyé ohun tí ó pilẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí gẹ́gẹ́ bí ìfáàrà ibi ni a ó ti sọ̀rọ̀ lórí èrèdí iṣẹ́ yìí ni a ti wọ́n aáyan àwọn ọ̀mọ̀ràn lórí oríkì níbẹ̀ ni a ti wo ohun tí oríkì orílẹ̀ jẹ́ Bákan náà a o wo ohùn tí àwọn aṣáájú ṣe lórí tíọ́rì ìbaráẹni gbépọ̀láwùjọ ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN ÌFÁÀRÀ Ohun tí orí kejì iṣẹ́ ìwádìí dálé lórí ni aáyan ọ̀mọ̀ràn lórí oríkì láwùjọ Yorùbá Bákan náá ni a ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìbáṣepọ̀ láàárín oríkì àti lítíréṣọ̀ alohùn yòókù a ó sí tún ṣàlàyé kíkún nípa tíọ́rì ìṣàmúlò Tíọ́rì ìmọ̀ ìbáraẹnigbépọ̀ wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ORÍKÌ NÍ ÀWÙJỌ YORÙBÁ Gẹ́gẹ́ bí èrò Ọlábímtán ní Oríkì jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí a fi ń da ẹni tó bá jẹ́ Yorùbá mọ̀ Ó tẹ̀síwájú láti ṣe àgbéyẹ̀wò oríkì àwọn orúkọ àmútọ̀runwá bí í Táyé Ìlọ̀rí Dàda àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Èrò rẹ̀ nípa oríkì orílẹ̀ pé Ó jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí a fi lè mọ ògidi èdè Yorùbá tó gbámúṣé kún inú oríkì orílẹ̀ fọ́fọ́ Lọ́nà mìíràn ó ní Oríkì orílẹ̀ ma ń rán wa létí ohun tí àtìrandíran bàbá bàbáńlá ìran kan ṣe nígbà ayé rẹ̀ Ó ń sọ nípa iwa iṣẹ́ àti akitiyan àwọn tí a bí sínú ìran tàbí orílẹ̀ yìí Ó tún rán wa létí ìtàn ìpìlẹ̀ wa láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ irú ènìyàn wo ní àwọn bàbáńlá wa jẹ́? Ohun tí ó sọ fún wa pé oríkì orílẹ̀ kì í bo àṣírí ìwà ikà tàbí ìwà rere kan tí àwọn ará wọ̀nyí bá hù Fún ìdí èyí oríkì jẹ́ orísun ohun àmúyangàn fún ọmọ abínibí Yorùbá Láṣebìkan ṣàlàyé pé; Oríkì ní í sọ ibi tí ènìyàn ti ṣẹ̀ bí wọ́n ti là tó àti oríṣìíríṣìí nǹkan akọni tí wọ́n ṣe gbogbo Ohun tí Láṣebíkan ń sọ ni pé ọ̀nà kan gbòógì tí a fi lè mọ ènìyàn dunjúdunjú ni nípasẹ̀ oríkì irú ẹní bẹ́ẹ̀ nítorí pé oríkì rẹ̀ yóò túṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ àti Gbàdàmọ́sí sọ pé oríkì ni Ohun tí àwọn onímọ̀ méjèèjì yìí ń sọ ni wí pé oríkì ni a fi máa ń ṣàpèjúwe ènìyàn tàbí fi gbóríyìn fún ènìyàn Adéoyè sọ pé; A sọ ọmọ ní sọ́de ó sebí sódẹ̀ a sọ ọmọ ní sóbọ̀ ó lọ àjò ó bọ A wá sọ ọmọ ní Sórìnlọ ó lọ sájò kò mọ pé ilé lọmọ ti mú orúkọ ànù lọ? Kókó ohun tí Adéoyè ń sọ ni pé orúkọ ọmọ ni ìjánu ọmọ Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ wí pé àkíyèsí tó gbọnngbọ́n máa ń wà kí a tó sọ ọmọ lórúkọ nítorí ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn ó máa ń ní ipa lórí ọmọ tàbí ẹbí lápapọ̀ bóyá ní èyí tí ó dára tàbí èyí tí kò dára Ọlátúnjí ṣe àlàyé lẹ́ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa bí oríkì ṣe ṣe pàtàkì tó láwùjọ Yorùbá àti bí ó ṣe jẹ́ ohun èlò tí àwọn ẹ̀yà Yorùbá kò lè ṣe aláìlò nínú ìṣe ojoojúmọ́ wọn Nínú àkóónú ó sọ báyìí pé; Oríkì Oríkì wúlò fún ẹni tí à ń kì nípa ṣíṣe àwọn àbùdá rere tí àwọn Yorùbá kà sí àti ṣíṣe àfẹ́rìí àwọn àbùdá tí kò ṣe é fi yangan Síwájú sí i nínú iṣẹ́ rẹ̀ kò ṣàì ṣe àlàyé lórí àwọn oríkì orílẹ̀ oríkì ọlọ́danni oríkì àwọn ọba ìlú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ó sì tún jẹ́ kí a mọ̀ wí pé ọ̀nà tí a ń gba gbé àwọn oríkì yìí kalẹ̀ le yàtọ̀ ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn Dáramọ́lá àti Jẹ́jẹ́ sọ̀rọ̀ nípa oríkì wọ́n ní; Oríkì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí tí àwọn Yorùbá máa ń fi yin ara wọn tàbí ẹni tí inú wọn bá dùn sí Yorùbá bọ̀ wọ́n ní kò ní í tán lára ọmọ ọba kó má ku dàńsáákì Ohun tí a rí fà yọ nínú rẹ̀ ni pé kò le burúburú nínú ìgbà oṣùn kí a má fi pa ọmọ lára kò le burúburú fún ọmọ ọba kí ó máa ní oríkì bọ̀rọ̀kìnní Àríwòye olùṣèwádìi ni pé àwọn Yorùbá a tún máa sọ oríkì àdájẹ́ oríkì orílẹ̀ ọmọ Àríwòye pàtàkì tí a tún rí níbi oríkì orílẹ̀ ni pé ó jẹ́ oríkì kan gbòógì tí ó wà fún ẹ̀dá kan tọkùnrin tobìnrin ni ó sì máa ń ní oríkì orílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá ORÍKÌ ORÍLẸ̀ Oríkì orílẹ̀ ni oríkì tí a mọ̀ mọ àwọn oríṣìíríṣìí àwọn ìdílé tí ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá Ohun mìíràn tí a lè pè ní oríkì orílẹ̀ ni oríkì orírun láti ara oríkì orílẹ̀ gbogbo ohun tí a bá fẹ́ mọ̀ nípa ènìyàn ni ó lè jẹyọ Adéoyè sọ pé ibi tí a bá mọ ọ̀nà dé là á ki ìlú dé Oríkì orílẹ̀ ṣe àfihàn bí ìran kan ṣe bá ìran kejì tan ní ilẹ̀ Yorùbá Ibi tí àwọn ìlú kọ̀ọ̀kan ti ṣẹ̀ pàtàkì púpọ̀ nítorí pé ó máa ń ṣe àfihàn bí ìran kan ṣe bá ìran kejì tan ní ilẹ̀ Yorùbá Ibi tí àwọn ìran kọ̀ọ̀kan ti ṣẹ̀ iṣẹ́ ìdílé ni ó lè jẹ jáde Bí àpẹẹrẹ nínú oríkì ọkọ̀ ni a ti gbọ́ pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹyẹ ẹ̀gà gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó máa ń fara hàn nínú oríkì orílẹ̀ Pàtàkì ni oríkì orílẹ̀ láwùjọ Yorùbá kò sí ìlú kan nílẹ̀ Yorùbá tí kò ní oríkì orílẹ̀ Àpẹẹrẹ bí ìhùwàsí ìlú ṣe lè jáde nínú oríkì ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú oríkì ìlú Ìbàdàn pé; Ìbàdàn ọmọ ajoròsùn Ọmọ afìkarahun fóri mu Ìbàdàn ibi olè gbé ń jàre olóhun Ẹni tí kò bá gbọ́ àlàyé ọ̀rọ̀ yìí á lérò pé Ìbàdàn ń fara kín olè ni ṣùgbọ́n ohun tí ó ń ṣe ni pé Ìbàdàn a máa bá ẹni tí ó bá jáfara pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ wí Yàtọ̀ sí èyí a tún rí nínú oríkì orílẹ̀ ìlú Oǹdó pé ènìyàn pàtàkì ni wọ́n ó lọ báyìí pé; Akínbínuadé Ará ìta Ìjámà Èkímògún ọmọ aládé igbó Iyẹ magogo ide mu omi Ọmọ lílà mẹ̀ríndínlógún ṣẹ̀yẹ Ohun tí oríkì orílẹ̀ yìí ń tọ́ka sí ni pé kò sí ààyè fún ọ̀lẹ àti ìmẹ́lẹ́ ní ìlú Oǹdó Níbi yìí ohun tí a rí fàyọ ni pé oríkì orílẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ìlú iṣẹ́ àti ìhùwàsí ìlú Gbogbo ìwọ̀nyí a máa jẹ jáde nínú oríkì nígbà tí àríwòye ènìyàn Ìrírí àti ẹni tí ó jẹ́ a máa sábà jẹ jáde nínú oríkì àbísọ àdájẹ́ ìnágijẹ àti bọ̀rọ̀kìnní ṣùgbọ́n gbogbo oríkì pátá ni ó jẹ́ ara àṣà Yorùbá ÌBÁṢEPỌ̀ LÁÀÁRÍN ORÍKÌ ÀTI LÍTÍRÉṢỌ̀ ALOHÙN YORÙBÁ MÌÍRÀN Láì ṣe àníàní ìran Yorùbá lápapọ̀ ló ni àṣà àti ìṣẹ̀ṣe Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wọ́n sì máa ń gbé èyí yọ nínú ìṣe wọn Èyí ló sún wa dé ibi lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ lítíréṣọ̀ alohùn jẹ́ iṣẹ́ ọnà tó ń ti ìran kan dé ìran kejì Kò sí ní àkọsílẹ̀ rárá Èyí ló bí òwe Yorùbá kan tó sọ pé ṣáájú kí àgbàdo tó dáyé ni adìyẹ ti ní ohun tí ó ń jẹ Fún ìdí èyí kí àwọn Òyìnbó aláwọ̀ funfun tó dé ni àwọn ìran Yorùbá ti ní ohun tí wọ́n ń pè ní lítíréṣọ̀ ti wọn Èyí sì ni lítíréṣọ̀ alohùn Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni a lè gbà rí lítíréṣọ̀ mìíràn ti máa ń bá oríkì pàdé Ìdí ni pé wọn jọ máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wọn Gbogbo wọn ni ó ń lo oríkì wọ́n kì í ya ara wọn nígbà kankan bí ti í wù ó mọ nítorí pé wọ́n ní ìbáṣepọ̀ pẹ́kípẹ́kí Àpẹẹrẹ díẹ̀ lára àwọn ewì Yorùbá mìíràn tí a ń bá oríkì pàdé ni ìjálá Ẹkùn ìyàwó rárà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Lára lára àwọn onímọ̀ tó ṣiṣẹ́ lórí ìjálá ni Yémiítàn ó sọ pé; Ìjálá ni àwọn ọdẹ fi máa ń sọ ìtàn oríṣìíríṣìí nípa ògún tàbí nípa ọdẹ ṣíṣe àti gbogbo ohun tí ọdẹ ń fojú rí nínú igbó Onímọ̀ mìíràn tó tún ṣiṣẹ́ lórí ìjálá ni Babalọlá nínú rẹ̀ ó sọ pé; Ìjálá ni ewì tí ògún máa lò ní ìgbà ayé rẹ̀ Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ìjálá ní í ṣe pẹ̀lú ògún ní gbogbo ọ̀nà ó jọ ẹni pé àwọn tí wọ́n bá ti ni nǹkan án ṣe pẹ̀lú ògún ni wọ́n máa ń sun ún ìjálá tọkùnrin tobìnrin ló máa ń fi ṣiṣẹ́ ṣe tí àwọn obìnrin sì máa ń sùnun lọ́ọ̀dẹ̀ wọn láti fi dárayá Àwọn tí ó jẹ́ àgbàtẹrù rẹ ganan ni àwọn ọdẹ Àwọn ọdẹ ló ni ìjálá láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wa Wọ́n sí máa ki ògún báyìí; Ògún torí obì o jẹkùú Ìjẹ̀ṣà Ogun jà wọ́n ogun ò kẹ́rù wọn Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ ṣáájú wọ́n tún máa ń ki oríkì ẹranko látàrí iṣẹ́ tí wọn ń ṣe tàbí nípa ìhùwàsí wọn Àpẹẹrẹ ni oríkì Ẹtu Ẹtu lárún Ọ̀bẹ̀jẹ́ ń yẹkẹ Abitete ológún ẹni fa Abiìjànjá í pe alàárù tantan Ẹtu mọ́ṣalá Ẹtu sàlàkọ́ Òfèfènfe ari ru tún raṣọ níwájú ọkọ Oríkì òkè yìí ń ṣe àlàyé bí Ẹtu ṣe rí ni Ẹtu jẹ́ ẹranko tí kò tóbi ṣùgbọ́n tí àwọ̀ ara rẹ̀ máa ń dán bọ̀lọ̀jọ̀ ó sì tún jẹ́ ẹni tí ó máa ń sare ó ní irun lára Ó sì tún jẹ́ ẹranko tí ó ní afínjú púpọ̀ ìjálá aré ọdẹ láti ọwọ́ Yémiítàn Bákan náà oríkì òkè yìí ń ṣe àlàyé bí ó ṣe rí Ọ̀kan lára àwọn ewì alohùn Yorùbá tí a ń rán lẹ́nu ni ìjálá èyí ni a mọ̀ sí Ìsàré Èyí tí ó túmọ̀ sí pé ọ̀nà ìgbéjáde rẹ̀ ni a fi sọ wọ́n lórúkọ Babalọlá ti ṣe onírúurú ìwádìí àkójọpọ̀ àti ìtúpalẹ̀ lórí ìjálá ohun tó farasin nínú ìjálá ni ìrèmọ̀jé Àwọn ọdẹ àti àwọn olùsin òrìṣà Ògún ló ni ìjálá Ìjálá sísun máa ń wáyé lásìkò tí àwọn ọdẹ bá ní ètò pàtàkì ṣe Ó lè jẹ́ àjọ̀dún ọdẹ tàbí lásìkò tí wọ́n bá ń bọ òrìṣà Ògún Ìjálá sísun kún fún oríṣìíríṣìí èròǹgbà lítíréṣọ̀ Òun náà sí máa fi àwùjọ Yorùbá hàn dénúdénú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà Dáramọ́lá àti Jẹ́jẹ́ sọ pé ìjálá kò ṣe fọ sí wẹ́wẹ́ láti fún ni ìtumọ̀ kan pàtó fún ọ̀rọ̀ tí a mọ̀ sí ìjálá Àwọn ọdẹ a máa dẹ ìgbẹ́ àdẹpọ̀ láti pa ẹran bóyá nígbà tí ẹnìkan nínú wọn bá ni ohun pàtàkì láti ṣe lásìkò ọdún ọdẹ tàbí ọdún ògún bí wọn bá pa ẹran tán nínú igbó Wọn a kó ara wọn jọ láti máa jó àti láti máa fi ìdùnnú wọn hàn Wọ́n a máa gbóríyìn fún orìṣà ògún pé ó mú kí ọwọ́ wọn yá Wọ́n a sí máa fi bí agbára ọdẹ ṣíṣe wọn ṣe ga tó hàn Wọ́n a kí ọdẹ aperin sí erin pípa Wọn a kí ọdẹ apẹkùn sí ẹkùn pípa pẹ̀lú Wọ́n a bẹ̀rẹ̀ ìlù àti ijó láti inú igbó títí wọn a fi dé àrín ìlú bí wọ́n ti ń jó bẹ́ẹ̀ ni wọn ó máa yín bọn fún òrìṣà ògún Oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni a lè gbà pín ewì Yorùbá lọ́nà kan a lè fi ojú ìlò wo ó Èyí ni àwọn ewì tó jẹ́ ti gbogbogbò tàbí tí ó jẹ́ ti àwùjọ Yorùbá lápapọ̀ bí í ìjálá ìwé tàbí ẹ̀ṣà egúngún ekún ìyàwó rárá òkú pípè òwe ọfọ̀ òkú pípè òwe ọfọ̀ eṣe ifá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Bákan náà ni àwọn kan wà tí ó jẹ́ ti àdúgbò lára wọn ni Alámọ̀ Èkìtì orin ọpa Ìgbómìnà olele ijẹ̀ṣà orin etíyẹrí Ègè Ẹgbá Lọ́nà mìíràn a lè fi ọ̀nà ìgbé jáde pín ewì Yorùbá sí ìsọ̀rí tí a bá ṣe èyí a lè tọ́ka sí ìsọ̀rí wọ̀nyí Ajẹ́mọrọ ẹnu àpẹẹrẹ oríkì ọfọ̀ òwe àlọ́ àpamọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Bákan náà ni a tún rí àwọn ewì tí a ń rán lẹ́nu tí wọn kọjá ọ̀rẹ́ ṣíṣọ pọ́ńbélé àpẹẹrẹ rárà yùngbà IwìẸ̀sà egúngún ìjálá ìrèmọ̀jé ìyẹ̀rẹ́Ifá òkúpípè àti àwọn tí o jẹ́ ti àdúgbò bí i olele àdàmọ́ olúngbé òsàré ipè ọpa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ TÍỌ́RÌ Yorùbá bọ wọn ni a kì í sòòṣà lódò kí làbẹlàbẹ̀ mọ́ mọ̀ A kò le ṣe àgbéyẹ̀wò tàbí ṣe iṣẹ́ lámèyítọ́ láì ṣe àmúlò ìlànà kan Ìlànà kan tí a ṣe àmúlò láti sọ nípa tíọ́rì Adéyẹmí sọ pé tíọ́rì ni abẹfẹ́lẹ́ ìmọ̀ tí a fi ń la ìfun àti ẹ̀dọ̀ onírúurú iṣẹ́ Ó sọ síwájú sí i pé nínú ìmọ̀ Sáyẹ́ńsì ni tíọ́rì tí jẹyọ àti pé ìwádìí yòówù ti kò bá gùnlé tíọ́rì kan nínú iṣẹ́ rẹ̀ irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ òfútùfẹ́tẹ̀ ni Ó tún fi kúnun pé tíọ́rì náà tún tí ìlànà kan tí a ti dánwò tí a sì rí i pé ó jẹ́ òótọ́ bákan náà Ọbafẹ́mi sọ pé Tíọ́rì ni irinṣẹ́ ìmọ̀ nípa ẹwà lítíréṣọ̀ láti jẹ́ kí ìbáṣepọ̀ ó wà láàárín ìran òǹkọ̀wé ìmọ̀ọ́nṣe rẹ̀ àti ìbánisọ̀rọ̀ tó péye Ohun tí Ọbafẹ́mi ń sọ ni pé àwọn ohun èlò fún àlàyé lórí iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ni tíọ́rì jẹ́ sọ báyìí pé Tíọ́rì ni lámèyítọ́ tí a ṣe lórí lámèyítọ́ kí iṣẹ́ lámèyítọ́ lè tẹ̀síwàjú Ọmọniyì ki tíọ́rì báyìí Ìlànà tí à ń tẹ̀lé láti ṣe ìtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ òun ní o dúró bí ìránṣẹ́ tí a ń lò fún ìtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ Ohun tí Ọmọniyì náà ń sọ ni pé láìsí tíọ́rì agogo ẹnu lásán ni a máa lù lórí ìtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ Ọ̀wọ́ méjì ni tíọ́rì yìí pín sí ọ̀wọ́ kìíní rí tíọ́rì lítíréṣọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí kò ni àjọṣe pẹ̀lú òǹkọ̀wé àwùjọ ni èyí tí ó jẹ́ pé a kò le ya lítíréṣọ̀ kúrò lára àwùjọ Ìpín kejì yìí ni tíọ́rì tí a fẹ́ ṣe àmúlò nínú Iṣẹ́ àkànṣe yìí ìyẹn tíọ́rì ìfojúìmọ̀ìbáraẹnigbépọ̀ wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀ TÍỌ́RÌ ÌFOJÚÌMỌ̀ÌBÁRAẸNIGBÉPỌ̀LÁWÙJỌ WO IṢẸ́ LÍTÍRÉṢỌ̀ Láì ṣe àníàní ó ṣòro kí a tó lè rí oríkì gbé e tán fún Soṣíọ́lọ́jì ṣùgbọ́n ohun tó jẹ mọ́ ìbáṣẹpọ̀ láàárín wọn ìrírí àwọn ènìyàn láwùjọ ni ohun tí irú ìrírí àti àjọṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ lè fà bá ẹ̀dá Soṣíọ́lọ́jì ni ènìyàn àwùjọ àti ìbágbépọ̀ wọn àti ipa tí irú ìbágbépọ̀ bẹ́ẹ̀ ní lórí àwùjọ Ó sọ síwájú sí i pé ohun tó jẹ Soṣíọ́lọ́jì lógún jù ni ìgbéayé ẹ̀dá ìwà rẹ̀ èdè rẹ̀ tí ó jẹ òpómúléró fún ìdúró ẹ̀dá láyé nínú èròǹgbà Soṣíọ́lọ́jì ni láti dáhùn àwọn ìbéèrè bí i Báwo ni àwùjọ ṣe ṣe? Báwo ló ṣe ń ṣiṣẹ́? Kíló fa ìdúró àwùjọ? Kí èyí tó lè ṣe è ṣe ìgbéléwọ̀n a máa wáyé lórí ètò àwùjọ ètò ọrọ̀ ajé ètò ìṣèlú àti àwọn nǹkan mìíràn tí ó parapọ̀ jẹ́ ètò àwùjọ Ohun mìíràn tó tún jẹ Soṣíọ́lọ́jì lógún ni ọ̀nà ìkọ́ni àwùjọ ìfòye àṣà kọ́mọlẹ́kọ̀ọ́ àti bí oníkalukú bí i ọba àgbà àgbà àti ọdẹ ìlú lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe ń gba ipa ti yóò kó láwùjọ kí ìlú ba à lè tòrò Onímọ̀ mìíràn tó tún ki Soṣíọ́lọ́jì ni ó sọ báyìí pé Nígbà kan rí àwọn ènìyàn a máa bára wọn ṣe nǹkan pọ Ìmọ̀ nípa ìbára ẹni ṣe pọ̀ yìí Ohun tí ń wí ni pé ìmọ̀ nípa ìbáṣepọ̀ láwùjọ àwọn ènìyàn ni Soṣíọ́lọ́jì jẹ́ Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìmọ̀ ìbáragbépọ̀ nìkan ni Soṣíọ́lọ́jì dúró lé ó tún máa ń ṣe ìwòye onírúurú ìyípadà tí ó dé bá àwùjọ Àwùjọ lè rọra máa yí padà tàbí kí o yí padà wìrìwìrì gbogbo èyí ni Soṣíọ́lọ́jì ma ń ṣe ìwádìí rẹ̀ Bákan náà Bísí Ògúnṣínà ki Soṣíọ́lọ́jì báyìí pé Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ Soṣíọ́lọ́jì jẹ́ àhunpọ̀ nǹkan méjì Soṣíọ́lọ́jì jẹ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìbákẹ̀gbẹ́pọ̀ tí ó ní ìbáṣepọ̀ àti ìgbẹ̀yìn fún ohun tí ó ní ìyípadà pẹ̀lú àwọn nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn látàrí ìbáṣepọ̀ tí wọ́n ni sí ara wọn Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ ìbákẹ̀gbẹ́pọ̀ yòókù Ohun tí ó jẹ́ Soṣíọ́lọ́jì lógún ni ìgbé ayé ẹ̀dá pẹ̀lú ìrírí ẹ̀dá ẹ̀dá pẹ̀lú àwọn tó ń tẹ̀lé wọ́n Ṣùgbọ́n ohun tó jẹ́ ajólórí Soṣíọ́lọ́jì ni àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn inú àwùjọ Ọ̀kan lára àṣà Yorùbá ni oríkì jẹ́ ìdí nìyí tí a fi lo tíọ́rì yìí fún ṣíṣe ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ yìí iṣẹ́ àti ìhùwàsí ẹ̀dá ènìyàn àti ohun tí ènìyàn ń ṣe ni àwùjọ ní o wa nínú oríkì tí a sì ń fi èdè tí ó dùn gbé e jáde Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ pé èdè tó dùn náà ni òpómúléró àṣà àti wí pé àṣà oríkì àti èdè tí a ń lò fi gbé e jáde inú àwùjọ ni gbogbo wọn tí jẹ́ jáde Èyí ni o mú kí a gbé àtúpalẹ̀ oríkì yìí ka orí tíọ́rì ìfojúìbágbépọ̀ àwùjọ wo lítíréṣọ̀ Èyí yóò sí jẹ́ kí a tún ètò àti àṣà ìbá gbẹ́pọ̀ àwùjọ ìlú Oǹdó sí ìta Ní àfikún ohun tí a ń sọ ni pé inú àwùjọ kan náà ni ènìyàn èdè àti àṣà tí jẹ́ jáde wọ́n sí ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ara wọn Yálà àṣà ilẹ̀ wa tàbí àṣà àtọ̀húnrìnwá àti àwọn aláṣà fúnra wọn Inú àwùjọ náà ni gbogbo wọn tí wá Kò sí àwùjọ kan tí kò ni àṣà àti iṣẹ́ tí ó ń gùnlé Ìdí nìyí tí a ṣe rí oríkì láti ara àṣà Yorùbá tí àwọn ìran Yorùbá lápapọ̀ sí ń gbé e lárugẹ ní gbogbo ìgbà Àtọba àtìjòyè àtọmọdé àtàgbà tó jẹ́ ìran tàbí ẹ̀yà Yorùbá pátá ni wọ́n ni oríkì tí wọn yálà ti àbísọ tàbí ti orílẹ̀ tó jẹ́ tí gbogbogbò tí ó sì jẹ́ pé inú àwùjọ ni gbogbo wọn tí wá tí ìbáṣepọ̀ tó lọ́ọ̀rìn sí wà láàárín wọn Ní àwùjọ ìlú Oǹdó tí iṣẹ́ yìí dá lé lórí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ìlú ilẹ̀ Yorùbá àwọn ẹ̀yà Yorùbá náà ló sí wá níbẹ̀ Àwọn àṣà tí a mọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ibẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mo àwọn ìlú ilẹ̀ Yorùbá fẹ́ràn oríkì nínú lítíréṣọ̀ alohùn wọn Wọn a máa lò ó níbi ayẹyẹ tí wọn bá ń ṣe Bí àpẹẹrẹ níbi ìkọ́mọjáde ìṣìlè ìgbéyàwó ìfinijoyé ìsìnkú tàbí lásìkò àwọn ọdún ìbílẹ̀ wọn gbogbo Oríkì yìí máa ń jẹ́ kí a ni ìmọ̀ nípa ẹní tí o ni oríkì gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú A ó mọ orírun àwọn babańlá rẹ̀ àti àwọn nǹkan akọni mìíràn tí wọ́n tí gbé ṣe nínú ìran wọn Bákan náà ó máa ń fi iṣẹ́ òòjọ́ àmúyẹ àti àléébù wọn hàn Bí a ṣe lè fi ṣe kóríyá fún ènìyàn Gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rí ni àwọn àwùjọ Yorùbá yòókù pátá náà ni ti àwùjọ ìlú Oǹdó ṣe rí MÁÀPÙ ÌPÍNLẸ̀ Oǹdó ORÍ KẸ́TA ÀWÙJỌ TÓ BÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌLÚ Oǹdó ÌFÁÀRÀ Ní orí kẹ́ta iṣẹ́ iwadiii yìí ni a o ti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọba tó tí jẹ́ ètò ìṣèlú wọn Àti àwọn ètò mìíràn tí ó ń mú ìlú Oǹdó yọ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ti i yọ ju orí lọ láàárín àwọn ìlú mìíràn ÌTÀN ÌṢẸ̀DÁLẸ̀ ÌLÚ Oǹdó Ìlú Oǹdó jẹ́ ẹ̀yà Yorùbá ni ìjọba ìwọ oòrùn ni ìpínlẹ̀ Oǹdó ìlú tí wọ́n sí bà pààlà ni ìlú Ìkálẹ̀ tí òun náà wà ní abẹ́ ìjọba Gúúṣù ìwọ oorun ni ìpínlẹ̀ Oǹdó Ní ayé àtijọ́ àwọn ènìyàn rí ìbejì gẹ́gẹ́ bí àmì burúkú wọ́n sí máa ń pa wọ́n lójú ẹṣẹ̀ tí wọ́n bá ti bí wọn Ní ayé ìgbà náà ọ̀kan lára ìyàwó Aláàfin Ọ̀yọ́ bí ìbejì ṣùgbọ́n ọba yìí nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ púpọ̀ Èyí ló mú kí ó gbìyànjú láti dáàbò bo ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ nípa rírán wọn kúrò láàárín ìlú lọ sí ibi tó jìnnà nígbà tí wọ́n fẹ́ máa lọ sí ìrin àjò yìí Aláàfin fún wọn ni ẹrú àti àwọn nǹkan mìíràn Ìtàn sọ fún wá pé nígbà tí wọ́n dé IléÌfẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀wà wọn Ọba Ọọ̀ni ṣe àdúrà fún wọn ó sí kọ àwọn ọmọ wọ̀nyí ni ilà kí o bà le fi dá wọn mọ̀ Wọ́n tẹ̀síwàjú nínú ìrìn àjò wọn Wọ́n de ibi kan tí a ń pé ní ita ìjámà láti ibẹ̀ wọ́n dé Ẹ̀pẹ́ ẹni tí ó jẹ́ olórí ìlú yìí sí tẹ́wọ́ gbà wọn Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ni wa ibi kan tí a mọ̀ sí Ilẹ̀Olújìí a fi ìgbà tí ó parí sí òkè kan ni Oǹdó tí a mọ sí Òkè Àgunlà Bí wọn ṣe débi òkè yìí wọ́n rí èéfín wọ́n sí tẹ̀lé ipa ọ̀nà yìí wọ́n pàdé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹkiri ọkùnrin yìí gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀ ó sì mú wọn lọ sí ibi kan tí a pé ni ìjọré ni ìlú Oǹdó Àwọn ènìyàn ìlú Oǹdó fi ọ̀kan nínú àwọn ìbejì yìí jé ọba àkọ́kọ́ wọ́n sí ń gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn Bákan náà ni a tún rí ètò ìṣèlú ìlú Oǹdó Ní ilé Yorùbá ọ̀nà tí wọn tí ó jé pé ọba ni aláàkóṣo ohun gbogbo ohun tí ó dájú ni wí pé igi kan kì í dá igbó ṣe Èyí ni wí pé ni inú àwùjọ kì í ṣe ọba nìkan ni ó máa ń dá àkóso ìlú ṣe ó pọn dandan kí àwọn ìjòyè jé amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tàbí alábàá ṣíṣe pọ̀ pẹ̀lú ọba Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ takuntakun ni àwọn ọba àti ìjòyè tó ti jẹ ní ìlú yìí tí gbé ṣe láti rí i wí pé ìlọsíwájú tàbí ìdàgbàsókè dé bá ìlú Oǹdó Nínú gbogbo ẹ̀dá kan ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run Yorùbá jẹ́ ẹ̀dá kan tí o kórìra ìwà ọ̀lẹ àti ìmẹ́lẹ́ wọn Yorùbá gbà pé iṣẹ́ ni oògùn iṣẹ́ wọ́n a máa sọ pé òṣùpá wù mi ju òkùnkùn ẹni tí ń ṣiṣẹ́ wùmí ju ọ̀le àti pé aríṣẹ́máṣe ní í sán fùrọ̀ lóògùn Ìgbàgbọ́ Yorùbá sì ni pé ènìyàn kò lè mú iṣẹ́ jẹ kí ó sì mú ìṣẹ́ jẹ àti pé àgbàlagbà tí ó bá ń la igi tà ó ti sinmi rẹ̀ léwe ni ẹ̀dá tí kò bà sì ṣiṣẹ́ yóò jalè Ní ìlú Oǹdó wọn kì í jí kí wọ́n káwọ̀ gbenú gẹ́gẹ́ bí a ti rí ìwà àti iṣẹ́ wọn Iṣẹ́ ni wọn máa ń múṣe Akíkanjú àti akin ènìyàn ni a mọ àwọn ará Oǹdó Onírúurú iṣẹ́ ni wọ́n sí yàn láàyò ní èyí tí o ń mú kí ìlọsíwájú ó máa bà wọn nínú ìlú náà yálà nínú iṣẹ́ ọdẹ ni tàbí nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ èyí tí ó jẹ́ iṣẹ́ àtìrandíran wọn tí ó sì ń mú kí ètò ọrọ̀ ajé wọn ó máa gbòòrò síwájú sí i tí o sí tún mú ìdàgbàsókè wọ ìlú wọn Ètò ẹ̀sìn náà kò gbẹ́yìn nínú ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Oǹdó Ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá ni pé Olódùmarè ni ó dá ayé tí ó sì tẹ̀ ẹ́ dó Òun náà ló sì dá àwọn ènìyàn síbẹ̀ kí wọ́n sì tún padà wá láti wá jábọ̀ Lẹ́yìn náà àwọn Yorùbá gbà wí pé wọ́n ní láti máa fi orúkọ Olódùmarè sí ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe láyé nítorí pé bí kò bá sí Olódùmarè ni kò le sí ẹ̀dá kankan Látàrí èyí ní ó ṣe jẹ́ pé kò sí ẹ̀sìn náà ni ilẹ̀ Yorùbá ti àwọn babańlá wa ń sìn tí wọn kì í ki Olódùmarè níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adẹ́dàá aṣẹ̀dá àti gẹ́gẹ́ bí ẹni tí í ó fi àṣẹ sọ̀rọ̀ tí ó sì ń fàṣẹ dáhùn sí onírúurú ìbéèrè ti ẹ̀dá bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ Ìran Yorùbá lápapọ̀ ló ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ké pe Olódùmarè pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé yóò dá àwọn lóhùn èyí yàtọ̀ ni ìlú sí ìlú ìletò sí ìletò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Irú ìlànà yìí náà ni a rí ní ìlú Oǹdó Ṣáájú kí ó tó di pé àwọn ẹ̀sìn àjòjì méjèèjì wọ̀lú Oǹdó ni wọ́n tí ó ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe ẹ̀sìn wọn; àti irú ìbọ tí wọ́n máa ń jẹ́sìn fún Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ́ pé ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ẹ̀sìn ìbílẹ̀ náà ló wọ́pọ́ ni ayé tí ìdílé kọ̀ọ̀kan nínú ìlú sí ni òrìṣà ìdílé tí wọ́n ń bọ yàtọ̀ sí òrìṣà tó jẹ́ tí gbogboo gbò bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń ṣe ní ìlú Oǹdó yìí láti ayébáyé Àpẹẹrẹ irú ọdún bẹ́ẹ̀ ni ọdún Gbélérù ọdún Ọlọ́kà ọdún Ìta Mafo ọdún Agẹmo ọdún Ògún ọdún Ajé ọdún Ọba ọdún Èkímògún ọdún Atakùnmọ̀ ọdún Ìfọ̀rẹ́ ọdún Olórí ọdún Ọba ọdún Ẹrínlà ọdún Lódún Ọdún oirì òṣémàwé àti otu ni Àjàlé òkèilé ni agogo mẹ́rin àárọ̀ kò sí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ kí ó tó di àárọ̀ Kété lẹ́yìn èyí ni ẹgbẹ́ òtú yóò máa kúnlẹ̀ fún àdúrà ni ọ̀dọ̀ òṣémàwé ní kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú obìí kọ̀ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òṣémàwé bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ olórí òtu títí kan olóyè kékeré láì ku olóyè kankan A kò sí gbọdọ̀ tan iná Wọn kò sí gbọdọ̀ rí ara wọn Èyí wà fún àdúrà pàtàkì pé ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ọba fẹ́ bẹ̀rẹ̀ Ọdún Ìfòré Ní ìgbà ọdún Ìfòré àwọn olóyè ìlú Oǹdó yóò mú oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn wá fún òṣémàwé Òṣémàwé yóò mú lára àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò gba ìlù fún ayẹyẹ ọdún Àwọn òpójì tí a mọ̀ sí òpò ilé yóò mú ìkájú ẹja ńlá àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ obì wà fún òṣémàwé Lẹ́yìn ọgbọ́n ọjọ́ ọdún Ìfòrè àwọn òpòjì yóò gbé obì lọ fún òṣémàwé ọba yóò gún méjìlélógún pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí àti iṣu tí yóò gbé fún Òyìnbó kan tí a mọ̀ sí olóyè gíga Lisa Lóbùn ÀLÀYÉ LÓRÍ ORÍKÌ ORÍLẸ̀ Oǹdó Oríkì orílẹ̀ ní àárín àwọn Yorùbá jé ohun tí o ṣe pàtàkì Oríkì orílẹ̀ ni àpapọ̀ oríkì àwọn babańlá àti àwọn ìyáńlá tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìtàn ìdílé olúwarẹ̀ oríkì orílẹ̀ jẹ́ oríkì tí ó ń júwe ìwà ìṣe babańlá àti ìyáńlá ẹni tí a ń sọ̀rọ̀ bá wọ̀nyí A kò le sọ ní pàtó iye àwọn oríkì orílẹ̀ Yorùbá ṣùgbọ́n àwọn tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú wọn tó mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n kókó ọ̀rọ̀ tó sì wà nínú oríkì orílẹ̀ ni ìwà ọmọlúàbí Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ inú oríkì máa yan ìtàn àtijọ́ àlàyé kíkún yóò sí kù sí ọwọ́ olùwádìí Ìgbà tí wọ́n bá ń kí ènìyàn ni ọ̀nà pàtàkì ní òwúrọ̀ kùtukùtù bí ọmọ bá ti dòbálẹ̀ tàbí kúnlè láti kí òbí rẹ̀ kú òwúrọ̀ Ìyá yóò lo gbólóhùn mélòó kan láti inú oríkì ìdílé wọn láti fi ki ọmọ náà tàbí nígbà tí ó bá lọ kí ìbátan àwọn òbí rẹ̀ tí kò rí fún ọjọ́ pípẹ́ tí ìbátan náà ba jẹ́ obìnrin gbàrà tí ó bá tí rí ọmọdé náà ni yóò tẹnu bọ oríkì orílẹ̀ wọn; yóò máa fi oríkì orílẹ̀ kí ọmọdé náà lọ bí ilẹ̀ bí ẹní ó le máa dẹ́nu dúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti wí pé ó káre ǹlẹ́ o kú àtijọ́ gbogbo àwọn arailé ńkọ́? àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Orí rẹ̀ náà yóò mu ara rẹ̀ a sí yá gágá pẹ̀lú ẹ̀rín múṣẹ́ Bákan náà nígbà tí àgbàlagbà bá ń ṣe àjọyọ̀ ní agboolé rẹ̀ nítorí ohun mìíràn oríkì orílẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n a máa fi kì í Síwájú sí i a tún rí oríkì orílẹ̀ ìlú Oǹdó pé ènìyàn pàtàkì ni wọ́n ó lọ báyìí pé Ará ìta ìjámà Èkímógún ọmọ Aládé igbó Ọmọ afi agogo idẹ mú omi Ọmọ onílà mẹ̀ríndínlógún ṣẹ̀yẹ Bákan náà ni a tún rí àwọn nǹkan to mú oríkì orílẹ̀ Òndó wáyé Láyé àtijọ́ ogun ni o ya tọkọtaya Ogun ní ó ya ìyá pẹ̀lú ọmọ Bí ọmọdé kò bá sí bá ìtàn ó yẹ kò bá àrọ́bá àrọ́bá sì ni bàbá ìtàn Ogun mú lélé lọ ẹ̀gbá alaké ìyá kò bí lélé ni ẹrú bàbá kò sí sọ ọmọ rẹ̀ ni ìwọ̀fà Àkúnlẹ̀yàn wọn ló tí wọ́n dé ọkọ ẹrú lóko ẹrú tí lélẹ̀ wà Ó múra ṣiṣẹ́ ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lélé ṣiṣẹ́ kára Ó sì ra ẹrú tó pọ̀ Lára ẹrú tí lélè tún rà ni mòrẹ̀ tún wà láì mọ Lélé pa àṣẹ wí pé kí mórẹ̀ máa lọ ògì Ìgbàkugbà tí mórẹ̀ bá tún lọ ògì ni ó máa ń kọrin tí ó bá sí tí ń kọrin yìí ni àwọn ọmọ olówó rẹ̀ ń fi etí gbọ títí wọ́n fi mọ orin náà kọ Wọ́n wa ń kọ orin náà ni ojú bàbá wọn Lélè Lélè gbọ ó ṣe hàá ẹnu ya bí àwọn ọmọ rẹ tí ń kọrin wọ́n ṣe àlàyé wí pé ẹrú titun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rà ni o máa ń kọ Lélè wá pé ẹrú o sí bẹ̀rẹ̀ orúkọ rẹ̀ ẹrú sí dáhùn pé Morẹ Lélè wá sọ fún Mòrẹ pé òun ni Lélè àbúrò rẹ̀ mọ̀rẹ̀ náà tún fi hàn wí pé òun ni mọ̀rẹ̀ àti wí pé ìyá wọn ni oólìbàbì Lélè wá pàsẹ wí pé kí àwọn ẹrú tó kù kí wọ́n pọ́n omi kí wọ́n sí wẹ mọ̀rẹ̀ Ìdí pàtàkì tí a fi ń jẹ oríkì ni wí pé kí a lè mọ ibi tí a ti wa tàbí bí a bá sọnù kí a le rí ara wa padà ORÍKÌ ÀWỌN ỌBA KỌ̀Ọ̀KAN Ní ìlú Oǹdó yàtọ̀ sí pé àwọn ọba wọn ń jẹ́ oríkì papọ̀ A tún rí díẹ̀ gbà nínú àwọn oríkì bọ̀rọ̀kìnní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn Èyí ni oríkì tí àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ fi máa ń kì wọ́n látàrí ohun ribiribi tí wọ́n tí gbé ṣe àti nípa pé wọ́n jẹ́ akikánjú ènìyàn oríkì bọ̀rọ̀kìnní ọba kọ̀ọ̀kan lọ báyìí ni ṣókí YÉSÀN Láte fẹ̀fẹ̀ Onísu to ta gbòngbò Ìyá ẹní aya aláya ṣe sọ Ó le eku wọ́nu ẹgàn pátápátá Ó na aya ẹní túká Ó bi ọmọ ẹbí ní Ọjọ́ dínkù ó ṣe tán olósùn ńlá Ó sùn gàdágbà légbè ọ̀run Ohun tí oríkì yìí ń sọ nípa rẹ̀ ni pé ọba yìí fẹ́ràn iṣẹ́ ọdẹ láìṣeyeméjì rárá Ó fẹ́ràn láti máa dẹ̀gbẹ́ ORÍKÌ ADÁJÀ A ń wa O fi agogo idẹ mọ tí Eléwù gbòho onikédìgbò Ó dá títí ọlá Ó gún le egbò Òkè Àlejó Àlajó gba ilé gbé Ádajà Eléwù gbòho Orílẹ̀ egbé Òkè àlejó ORÍKÌ JOMU Òyàn onídà Òyànyán onimú Ogbogbo létí Ó ṣe ọwọ́ bàbá núdà Egún ńlá o Ó pá ayé run Ó pa ifọ̀ láyìnmí Ó pa onígbọ̀wọ́ Ó dà jẹ ẹran mìmìmì Ó fi ọwọ́ gbọ́ ifá Ó ń àyé láìláì Ó dàgbà lọ́dọ̀ èṣù ORÍKÌ LÓSÙNLÁ Ajágìgì oògùn Olókè mẹ́ta Òkòkò Balógun Ó dúró lókè Ó sọmọ di pùyé pùyè Òkè gbọ́mọ di tilolo Ologun tí kà di Odidi mọndè Ojú ogun láwé sawé ORÍKÌ LÓGBÒSÉRÉ Ató àgbà gbọngbọn Ó kó ẹbí mọ́ra Ó pàlàngà ẹbí Ó mú gogo rẹ̀ ṣe Ó fi pópó nu ojú ORÍKÌ ARÓGBÓ Àgbède onígèlè Ọkọ pupa Ó lọ sòko Elétí arógbó Ọba kú kegun Elete dèyìn Olè lébà onílé Arógbó ilà ṣẹ̀gi ORÍKÌ LÓYÌNMÍ Òkè odò Alájé orùn akingbájìn Ó ṣe pẹ̀lẹ́ Oní pẹ̀lẹ́ Ajerú mo boku ṣenu Òrún to Ato Ató ọba nífẹ̀ Ìgbésí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ Lóyìnmí aláte ìlèkè ÀYÀDÌ Ìyálà lepegun Ó mú aṣọ ọba Ó mú idà Ó fi idà sẹ́yìn Ó fi idà jẹṣu Ó sojú kókó Alálè orò tí Sun ọmọ ayé jẹ Àyàdì légbàdà Ó kò inà léyìn jọyọ ORÍKÌ ÒṢÉMÀWÉ Kábíyèsí àbá ìyé Ikú alaṣẹ Ògbìgbà gbọmọ là Ó la lóni o Ó jìwàjiwa ìlẹ̀kẹ̀ Ó sọkọ àkókó Alagbára jeni níyà Afèrín sí Ikú aláṣẹ èkejì òrìṣà ORÍKÌ AJISÓWÓ Ọtún owó Ọmọ afèrì wọ̀wọ̀ Sọrọ méjì Ajisówó Ọmọ Lísà pátákó Aṣọ orúkọ oníbàràká Òtẹ̀lú òrèrú o fi Owí erú jọba Ará ìgúrì ÀWỌN ỌBA TO TÍ JẸ́ ÀTI ỌDÚN WỌN Pùpùpù ọdún mẹ́rìnlá Airo ọdún mọ́kanlélógún Lújù ọdún mọ́kanlélógún Òkùta ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n Lúyaré ọdún mọ́kàndínlógún Fòyì ọdún mọ́kàndínlógún Léyò ọdún mọ́kàndínlógún Gbayi ọdún mẹ́tàdínlógún Liyen ọdún mẹ́tàdínlógún Bàjùmú ọdún mẹ́tàdínlógún Aperuwa ọdún márùnún Gbede Gbede Làmolè ọdún márùndínlógún Aganmede ọdún mọ́kànlá Olowolaiye ọdún mẹ́tàdínlógún Jógundè ọdún mọ́kànlá Térere ọdún mẹ́rindínlógún Ajímósó ọdún mẹ́rindínlógún Árobiréré ọdún mẹ́sànán Ayanlọlá ọdún mẹ́ta Ọdúnọla ọdún márùnún Jílù ọdún márùnún Olówólakun ọdún márùnún Jíwòmó ọdún méje Jílàlá ọdún mọ́kànlá Jímósùn ọdún mẹ́sànán Afunbiye ọ̀dúndún ọdún méje Arílékọ́lásì ọdún márùnún Jímosùn ọdún mẹ́rin Ọ̀ṣungbádelọlá ọdún mẹ́ta Ayíbíkíwòdì ọdún márùnún Afàìdùnóyè ọdún márùnún Jímẹ́kùn DÍẸ̀ NÍNÚ ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ỌBA ÌLÚ Oǹdó Ní ilẹ̀ Yorùbá ní ayé àtijọ́ tí wọn ba tí bí ìbejì wọn a pa wọ́n nítorí abàmì ọmọ ní wọ́n kàásí lásìkò yìí ni wọ́n bí Òsárewásakin ọmọ ọba Olááso ni aláàfin Ọ̀yọ́ ó sí ni ìyàwó púpọ̀ Ó fẹ́ràn ìyá àwọn ọmọ wọ̀nyí kò sí fẹ́ pa wọ́n Ó kó àwọn ìbejì náà pẹ̀lú ìyá ránsẹ́ sí Epinni ni ìlú àwọn Ìbàrìbá Nígbà tí ọba Oluaso tẹ̀rí gbaṣo ní ọba Onígbogí jẹ́ tẹ́lẹ̀ Onígbogí jẹ́ obìnrin tí o jẹ́ ọba ni kò fé kí wọn fi ìyá jẹ wọ́n ó sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ ìjà kí ó kọ wọ́n kúrò ní ìlú gba ọ̀nà IléÌfẹ́ Ìjẹ̀bú ọba Ọọ̀ni sí tún ràn wọ́n lọ́wọ́ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lò tẹ̀lé wọn títí wọ́n fi de ìlú Ẹ̀pẹ́ Láti ìlú Ẹ̀pẹ́ ni wọ́n tí rin ìrìnàjò wọn dé ibi ìdíèdó pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọmọ náà tó túmọ̀ sí EseOmore títí o fi di Òṣemàwé tí ìdíèdó sí da Oǹdó Ọba pùpùpù Gẹ́gẹ́ bi a tí gbọ́ nínú ìtàn pé ìjọba rẹ̀ dára Ó fẹ́ràn àwọn ohun ọ̀sin púpọ̀ gẹ́gẹ́ bi a tí gbọ pé àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ jọ ń ṣe ìpàdé pọ̀ ó kúrò lọ́dọ̀ wọn ó lọ mójútó àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ Irú ìwà yi bí wọn nínú tí wọ́n sí pinnu wí pé àwọn kò ní fi obìnrin jẹ ọba mọ́ ni ìlú Oǹdó Ọba Airo Lẹ́yìn ikú ọba Pupupu ni ọba Airo tẹ̀lé ìyá rẹ̀ ó sí kéré nígbà tí ó jẹ́ ọba ṣùgbọ́n Àyàdì lọ ń tọ sọ́nà ó sí ń ba ṣe ìjọba rẹ̀ títí tí o fi le ṣe ìjọba fún ra rẹ̀ Ó dá ẹgbẹ́ Àyàdì àti ẹgbẹ́ òrúnbátó sílẹ̀ ní ọjọ́ kan ó ṣe ìpèdè pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ sí pààrọ̀ oyè wọn Ó mú Lísà ṣáájú Jomu ó mú ọ̀dunwò ṣáájú sàseré Ó pààrọ gbogbo wọn ó mú ẹni tí ó ṣáájú lọ sí ẹ̀yìn Nítorí ìwà yìí ni àwọn ìgbàanì ṣe ń pè ní Airo ìjọba rẹ̀ sí dára Ọba Lújù Nígbà tí ọba Airo tẹ́rí gbaṣọ ni ọba Lújù bọ sí orí ìtẹ́ kò tó di ìgbà tó jẹ ọba ni àwọn baálẹ̀ Yorùbá máa ń lọ bá ọba Ọ̀yọ́ ṣe ọdún tàbí kí wọn rán àwọn oníṣe wọn lọ pẹ̀lú ẹ̀bùn Kété tí ọba Lújù gún orí oyè ní ó lọ farahàn aláàfin ní Ọ̀yọ́ Nígbà tí ó wà ní Ọ̀yọ́ o fi ojú sí bí ọba Aláàfin tí ṣe kọ́ ààfin rẹ̀ Ọba ají bóyèdé ló wà lórí ìtẹ́ Bí Lújù ṣe tí Ọ̀yọ́ dé ó sọ fún àwọn ará ìlú Oǹdó kí wọ́n kò irú ilé yìí Ogun bẹ́ sílẹ̀ ni ìlú Oǹdó tí o sí ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun jẹ́ kò sí àlàáfíà Ìjà yìí pọ̀ tó jẹ́ pé wọ́n kó lára àwọn Oǹdó lẹ́rú; wọ́n sí ṣẹ́gun àsìkò yìí ni Jomuńlá yọ sí wọn ó pa púpọ̀ nínú wọn Lẹ́yìn ogun yìí ni ọba Lújù ṣe oògùn fún Oǹdó pé ogun kò ni jà Oǹdó mọ láéláé Ó sí rí igi ẹ̀gún káàkiri ìlú ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe kọ́ ilé sẹ́yin igi yìí Àwọn Oǹdó kò sí kọ́ ilé sí ẹ̀yìn odi ìlú nígbà náà Ọlọ́run sì gbà bẹ́ẹ̀ fún ọba yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló ṣẹlẹ̀ lásìkò ọba Lújù àwọn ọmọ rẹ̀ ni òkúta Lúyàré Fòyì àti Lẹ́yò Ọba Lúyàrè Kò sí ogun tàbí ọ̀tẹ̀ lásìkò tirẹ̀ ọmọ Lújù sí ni Ó sí jẹ́ kí àwọn Oǹdó máa pe ọmọ ìyá kán náà ni gbogbo wọn ó ń ba àwọn Oǹdó kẹ́dùn tí ọfọ̀ bá ṣẹ̀ wọ́n ó sí ní àánú púpọ̀ fún ara ìlú rẹ̀ orúkọ rẹ̀ sí gbilẹ̀ lásìkò tirẹ̀ Ọba Fayi Ọba alákínkanjú ló jẹ́ ó sí jẹ́ ọmọ ọba lúyàré kí ọba yìí tó jẹ ni àwọn ara ìlú Àmọ̀ná díde ọ̀tẹ̀ tí wọn sí ba ìlú jẹ́ ṣùgbọ́n ó dìde bí akọni ó jẹ́ dódun tí ó bá de ojú ìjà a mú kí òòyì máa kọ àwọn ọ̀tá rẹ̀ lójú títí o fi gba àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ ìdí tí wọ́n ṣe ń pé ni ọba Fóyì ni èyí Ọba Lẹ́yọ̀ Ọba Lẹ́yọ̀ ni o jẹ ọmọkùnrin tí ó kéré jùlọ nínú ọmọ ọba Lújù ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n Ó sí jé ọ̀rẹ́ sí ọba Ayíbí ọba Aláàfin Ọ̀yọ́ ṣe ọ̀rọ̀ ìmùlẹ̀ Nígbàkúùgbà ní ọba yìí ń fi àwọn ọmọ ògún ránṣẹ́ sí í ó sì máa ń ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀ Ọba Gbàjì Ọba gbàjì jẹ́ ọmọ ọba òkúta ó kéré nígbà tí ó jẹ́ ọba kò sì olùdádàmọ̀ràn kan fún kò sí gbọ́n púpọ̀ Oǹdó sí rẹ́ ẹ jẹ́ Irú ìwà játi jàti yìí ló mú kí ó máa hu ìwà àíbìkítà sí àwọn Oǹdó kí o tó wá di pé gbogbo rẹ̀ rọlẹ̀ díẹ̀ Ọba Liyen Ó jẹ́ ọmọ ọba lújù ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ìjẹ̀bú olóògùn ni ọba yìí oríṣìíríṣìí egbògi lò wà lọ́wọ́ rẹ̀ kí o tó wá jẹ ọba Oǹdó sí fẹ́ràn rẹ̀ ó ma ń ṣe oògùn fún aláboyún ọmọdé àti àgbà Kí o tó kúrò ni Ìjẹ̀bú ó mú òrìṣà Ifá àti agẹmọ wá sí Oǹdó lẹ́yìn ìgbà tí ọba yìí tẹ́rí gbaṣọ àwọn ènìyàn fẹ́ràn láti jẹ́ kí ọmọbìnrin kan ṣoṣo tí o ni di òṣémàwé nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ni sí ọba yìí ṣùgbọ́n àwọn Oǹdó tí ṣe ìbúra pé obìnrin kò jẹ ọba ní ìlú Oǹdó mọ́ ORÍ KẸ́RIN FÍFI TÍỌ́RÌ ÌBÁGBÉPỌ̀ ÀWÙJỌ ṢÈTÚPALẸ̀ ÀWỌN ORÍKÌ ORÍLẸ̀ ÒNDÓ ÌFÁÀRÀ Oríkì ṣe pàtàkì láàárin àwọn Yorùbá ó máa ń tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn nǹkan tí kí bá fi ara sin nípa ẹni tí ó ni oríkì Oríkì jẹ́ ewì gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Oyèrìndé tí ó sọ pé sọ pé ewì alohùn jẹ́ òtítọ́ ju ìtàn lọ Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀ a jẹ́ pé ó sàn kí a ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn oríkì àwọn ọba ìlú Òndó kí a ba le rí kókó kan dì mú nípa àwọn ọba wọ̀nyí Àwọn nǹkan tí ó ṣe pàtàkì tí a lè rí nínú oríkì àwọn ọba ìlú Òndó ni ètò ọrọ̀ajé ìbágbépọ̀ àwùjọ Bákan náà ni a tún rí àwọn kókó mìíràn bí ìfaradà wọn agbára wọn iṣẹ́ wọn ọgbọ́n wọn ìtàn wọn àti ìwà wọn ÀGBÉYẸ̀WÒ IPA ÀTI IPÒ ÀWỌN ỌBA NÍ ÌLÚ ÒNDÓ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ ènìyàn lásán kò le jẹ́ ọba ní ìlú Òndó bí kò ṣe akọni ènìyàn A lè mọ ipa àwọn ọba wọn nípasẹ̀ ìwà akin wọn àti agbára tí wọ́n ní pẹ̀lú Tí a bá wo ẹni tí ń jẹ ọba ní ìlú Òndó a máa rí i pé olórí ogun ni Èyí fihàn pé a lè mọ ipa àwọn ọba nípasẹ̀ ipò wọn Díẹ̀ nínú àwọn tó jẹ ọba OYÈ IPÒ Olóyè Àyàdí Ijámà Olóyè Òrúnbátó Lótù ìjámà Olóyè Légírí Líyé majà Olóyè Àrùwá Láogo Ijámà Olóyè Lódàsá Itáwuyì Ijámà Olóyè Lóyìnmi Lójòjò Ijámà Olóyè Sòkòtí Lotogbe Ijámà Báyìí ni ipò àwọn olóyè tí ó jẹ́ ọba ní ìlú Oǹdó Àwọn ipò yìí jẹ́ pàtàkì ó sì tún jẹ́ ipò fún àwọn alágbára pẹ̀lú Ipò àwọn ọba yìí kì í ṣe nǹkan tí a lè fojú tẹ́ńbẹ́lú tí ìlú bá ń dára ó kù sí ọwọ́ ọba tí eku kò bá ké bí eku mọ́ tí ẹyẹ bá ń ké bí ẹyẹ kò ba sì ké bí ẹyẹ mọ́ ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí ọba ni olùdarí ìlú Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ ọba ni olórí ohun gbogbo ipa ọba ni láti pàṣẹ fún ìlú tí àṣẹ náà sì gbọdọ̀ múlẹ̀ Ipa àwọn ọba Oǹdó ni pípa àṣẹ gẹ́gẹ́ bí ipò tí wọ́n wà Lára àwọn ipa ọba ìlú ni láti to ìlú wọn wọ́n a máa to ìlú kí rúdurùdu má ba à le wáyé èyí sì jẹ́ pàtàkì lára ipa àwọn ọba yìí kí alaafia le bá a jọba ní ìlú Òndó Bákan náà ni a tún rí àwọn Ìwàrẹ̀fà tí ó ní ipa tí ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ń kó ní ìlú Oǹdó kí ìjọba ó lè rọrùn ní ṣíṣe wọ́n máa ń yan àwọn ìjòyè láàárín ìlú sí àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan tí ìbáṣẹpọ̀ wọn sì máa ń dánmọ́rán Bí àpẹẹrẹ OYÈ IPÒ Olóyè Òrúntó wà fún Òkèlísà Olóyè Arógbó òkè odunwo Olóyè Lógbòsẹ́rẹ́ ọ̀rérétu Olóyè Sàsọ̀rẹ odòsídà Olóyè Jomu Lẹ́gírí ìdí Lẹ́gírí Bákan náà ni a tún rí àwọn ìgbìmọ̀ olùdámọ̀ràn ọba tí ó j ewì pé ojúṣe wọn ni yíyan ọba sí ipò Ó ní àwọn ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé ní yíyan ọba sí ipò ní ìlú Oǹdó Lára àwọn olóyè ni ó máa ń kópa nínú àwọn ètùtù ìfijoyè Ìlànà tí wọ́n máa ń lò nìwọ̀nyí Ì GBÉSẸ̀ ÌFINIJOYÈ ỌBA ÌLÚ ÒNDÓ ÌGBÉSẸ̀ KÌÍNÍ Àwọn olùránṣẹ́ tí a ń pè ní òdìbò Lísà Jomu òdunwò sàsọrẹ́ àti Adájà ni yóò sin àwọn olóyè àti ṣamọ̀rà lọ sí abúlé láti lọ mú òṣèmàwé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn Wọn yóò sọ fún un wí pé wọ́n wá láti wá mu nítorí ìbáṣẹpọ̀ tí ó ní pẹ̀lú ìyàwó olóyè gíga Lísà Lẹ́yìn tí òṣemàwe tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn bá ti tako ẹ̀sùn yìí ni wọn yóò sọ fún pé àwọn ará ìlú Oǹdó ni ó fẹ́ kí ó jẹ òṣemàwe ti ìlú Oǹdó yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn bẹ́ẹ̀ ni yóò sì ta wọ́n lọ́rẹ ewúrẹ́ kan ÌGBÉSẸ̀ KEJÌ Olóyè Lísà sàsọrẹ́ yóò mú òṣèmawé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn lọ sí ilé olóyè Lísà ni òkèlísà ní àdúgbò lákó ní nǹkan bí déédé agogo márùnún àárọ̀ ọjọ́ kejì tí ó bá dé ilé rẹ̀ Níbẹ̀ ni àwọn Ìwàrẹ̀fà yóò ti ṣe ayẹyẹ ìkọlà ojú fún òṣemàwé Egbò ilà yìí gbọdọ̀ san láàárín ọjọ́ méje tí ó jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ rí wọn lásìkò náà Lẹ́yìn ọjọ́ méje oṣù mẹ́ta wọ́n ní láti parí gbogbo ètò yìí gbogbo àwọn olóyè ni wọ́n yóò ránṣẹ́ sí láti wá kó ipa tí ó tọ́ sí ẹnìkọ̀ọ̀kan láti kó nínú ètò ìfijoyè yìí ÌGBÉSẸ̀ KẸ́TA Nígbà tí ó bá ku ọjọ́ méjì tí àwọn ayẹyẹ wọ̀nyí yóò bẹ̀rẹ̀ àwọn olùbọ olóyè márùnún tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ekìrì Ọbalúfọ̀n Súmọ́ Sàò sanyìn àti ọlọ́jà dókò ni yóò lọ sí ilé olóyè gíga Sàsọré láti mú Òṣemàwé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn lọ sí ojúbọ tí ó wà ní ọ̀nà Èpè fún ètùtù kí wọ́n tó kúrò náà yóò ti ta aṣọ funfun mọ́ lọ́rùn Nígbà náà ni wọn yóò mu lọ tààrà sí ilé ọlọ́jàDókò tí wọ́n bá ti dé ìlú Lẹ́nu ibodè tí ó kángun níbi tí ọlọ́jàDókò tí ń dúró dè wọ́n ni yóò ti bọ aṣọ funfun ọrùn Òṣémàwe tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn Lẹ́yìn èyí ni wọ́n yóò kẹ̀yìn sí ara wọn èyí tí ó fi hàn pé Òṣemàwé tuntun yìí kò gbọdọ̀ gbá ilé ọlọ́jà Dókò mọ́ Àwọn olùbọ olóyè yìí yóò máa mú Òṣemáwe padà lọ sí ilé olóyè gíga Sàsọré IPA ÀTI IPÒ ÌLÚ ÒNDÓ NÍPA OGUN JÍJÀ Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ipa àti ipò Oǹdó nípa ogun jíjà Oǹdó kì í ṣe nǹkan tí a lè fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ogun jíjà Ogun jíjà ni ó sọ Oǹdó di ìlú tí ipò rẹ̀ ga ní àwùjọ Yorùbá lónìí yìí Bákan náà tí a bá wo ọba pùpùpù tí ó tẹ ìlú Oǹdó dó alágbára ni jagunjagun sì ni pẹ̀lú Agbára akínkanjú tí àwọn jagunjagun Oǹdó jẹ́ kì í jẹ́ kí àwọn ara àdúgbò wọn le è kọ iyán wọn kéré Wọ́n máa ń fi Oǹdó sí ipò ńlá nípa èyí Ènìyàn kò le è ni ipò tó ní láárí ní ìlú Oǹdó bí kò bá jẹ́ akọni Akọni ni ó ń di ipò mú ní ìlú Oǹdó Wọ́n sì máa ń yàn wọ́n sípò nípa ipa tí wọ́n ti kó sẹ́yìn Bí àpẹẹrẹ ọba Bàjùmù tí ó jẹ́ alákínkanjú bí bàbá rẹ̀ ó lọ sígun bá ìlú kan tí ó súnmọ́ Oǹdó nígbà tí ó gbọ́ pé wọ́n fẹ́ máa jẹ gàbalé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí IPA ÀTI IPÒ ÀWỌN ỌBA ÌLÚ ÒNDÓ GẸ́GẸ́ BÍ ALÁGBÁRA Àwọn ọba ìlú Oǹdó jẹ́ olórí ogun Wọ́n lágbára wọ́n sì jẹ jáde nínú oríkì wọn Oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí wọ́n gbà fi agbára hàn ló wà nínú oríkì wọn Àpẹẹrẹ èyí jẹ jáde nínú oríkì ọba òkúta Òyán onídà Òyanyàn nímú Ògbogbò létí Ó ṣe owó ọba onídà Egún ńlá o ilà Gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú oríkì wọn a tún rí àpẹẹrẹ agbára oògùn tí ó jẹyọ nínú oríkì ọba Lósùnlá Ajagíjigì oògùn Orìṣà Ẹ̀gbá kúkú Olókè mẹ́ta Ó sọmọ di pùyépùyé ilà Yàtọ̀ sí agbára oògùn tí àwọn ọba wọ̀nyí ń lò wọ́n kápá àwọn ènìyàn dáadáa wọn a sì máa lo agbára àti ipò wọn lórí àwọn ènìyàn wọn Àpẹẹrẹ èyí hàn nínú oríkì Jomu Ó pa baba wọn run Ó pa ayé run Ó pa onígbọ̀wọ́ Ó dá jẹ ẹran mínímíní Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú òkè yìí Jomu tí ó ni oríkì yìí náà le ní ẹ̀dá Bákan náà agbára wọn pọ̀ dé ibì kan dé ibi pé wọn a máa fi ìyà jẹ ìjòyè ìlú wọn kò sì bẹ̀rù àjẹ́ nítorí wọ́n ní agbára OGUN JÍJÀ Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀rí tí a ti rí fàyọ nínú oríkì àwọn ọba yìí a tún rí ẹ̀rí mìíràn tó tún fúnka mọ́ ọn pé yàtọ̀ sí pé wọn lówó wọ́n lọ́lá wọ́n nípò wọ́n ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti rí i pé ogun kò ja àwọn ènìyàn wọn Wọ́n ní agbára láti jagun ṣẹ́gun Àpẹẹrẹ èyí ni a rí nínú oríkì ọba Àfaidùnjoyè àsìkò ọba yìí ni wọ́n lọ ṣígun bá Ìrelé ní ìgbà kejì ọmọ ọba Arógun má tìdí Àjànàkú sọwọ́ ìjà sókè Ọmọ aródẹ́dẹ́ wọnú ogun Ọmọ afẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́jẹ̀ wẹ̀ IṢẸ́ ÒÒJỌ́ WỌN Yàtọ̀ sí pé wọ́n máa ń ta kókó wọn kì í fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú iṣẹ́ àgbẹ̀ ní ṣíṣe ní ìdílé wọn Wọ́n a sì máa ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú oko wọn àti pé iṣẹ́ àgbẹ̀ yìí sì máa ń sọ wọn di olówó púpọ̀ orokoroko gbọwọ́ ọ fújà Kì í sọmọ ìbílẹ̀ lo ṣe lọ Ó mókó nílé Ó mú àdá nílé Ó dágbádá wọnú oko Bákan náà ojúlówó iṣẹ́ wọn àwọn ọba ìlú Òndó ní láti dábò bo àwọn ara ìlú Àpẹẹrẹ èyí wa nínú oríkì ọba Àpèrúwà Ará ìjámá Ó sékẹ̀ ará ìlú Ó sèké Àlejò Àlejò gbàgbé ilé ÈTÒ ÌṢÈLÚ Onírúurú ọ̀nà ni àwọn Òndó ń gbà ṣe ètò òṣèlú wọn Wọ́n ń ṣe àwọn nǹkan yìí kí ìlú ba à lè tùbà tùṣẹ A lè rí lára ọ̀nà òṣèlú wọn Ọba Ìbídàpọ̀ Adédìísẹwo Adésànájè ní kété tí ọba yìí gorí oyè ó ṣe àbẹ̀wò sí gbogbo agbègbè tí ó wà ní Oǹdó láti rí i pé ìfẹ́ àti àlàáfíà wà Ó rí i pé ìlú Oǹdó ń gbé ayé ìrọ̀rùn ó dá agbègbè márùndínlógún mìíràn sílẹ̀ Ijámà Ọba yìí jẹ́ onígbàgbọ́ tí ó sin Ọlọ́run bí ó ti yẹ Àsìkò rẹ̀ ni wọn dá ìjọba Oǹdó sí méjì ìlà Oòrùn àsìkò yìí ni wọ́n gbìmọ̀ láti sọ ilé ẹ̀kọ́ gbogbońṣe di Fásitì Olówó ni ọba Adésanoyè kí ó tó jẹ́ ọba ìlú Oǹdó olówó jaburata ni Ó kọ́ ààfin ìgbàlódé fún àwọn ará ìlú Òun ni ọba kejì tí ó lọ sí ilẹ̀ọba ÒkèÒkun Ní kété tí ó dádé lẹ́yìn ọdún mẹ́ta ni ọmọ bíbí ìlú Oǹdó di Gómìnà ìpínlẹ̀ náà Òun ni Dókítà ọmọ bíbí ìlú Oǹdó tí ó jọba ó sì tún máa fún àwọn aláìní lówó ó sì tún fi owó rẹ̀ kọ́ ilé Ọlọ́run àti mọ́sálásí ó gbìyànjú nígbà ayé rẹ̀ Ọba yìí ṣe ohun máànígbàgbé sí Oǹdó ó fẹ́ràn ijó àti orin ìgbàgbọ́ púpọ̀ Ọba yìí kò gbà kí wọ́n fi owó du oyè mọ́ Ìgbà ọba yìí ni wọ́n kọ́ ọjà tuntun tí ó wà ní sábó Ó ṣe gudugudu méje àti yàyà mẹfà fún ètò àti ìlọsíwájú ìlú Oǹdó Ìmúra Bákan náà a máa rí i pé ìmúra wọn jẹyọ nínú oríkì wọn Ọmọ àfẹ́rí wọ̀wọ̀ sọrọ̀ Aji ṣówó otùn ọwọ́ Ekejì ìlẹ̀kẹ̀ Ọmọ Aládé igbó Òjiwà jiwa ìlẹ̀kẹ̀ Bákan náà ní ìlú Oǹdó ìmúra wọn máa ń yàtọ̀ sí ara wọn Ìdí èyí ni wí pé àwọn ará ìlú yìí yóò tètè mọ̀ iru ẹgbẹ́ tí wọn wà Èyí ni à ń pè ní ìpelè ṣùgbọ́n lóde òní olóyè àti ẹni tí kò jẹ oyè máa ń múra láì mọ̀ ìtumọ̀ wọn Èkíní Àwọn òtú máa ń fi tiwọn kọ́ ọrùn ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì yìí yóò kọjá àyà Èkejì Àwọn ọ̀túnba wọ́n a fi aṣọ tiwọn kọ́ ọrùn ọwọ́ rẹ̀ yóò sì lọ sí ẹ̀yìn Bákan náà ni a tún rí àkún ọwọ́ àti ti ẹsẹ̀ tí ó wà fún ọba pẹ̀lú àwọn Ìwàrẹ̀fà nìkan ṣùgbọ́n àwọn olóyè tó kù le wọ àkún sí ọwọ́ kan ṣoṣo Gẹ́gẹ́ bí òwe ilẹ̀ Yorùbá pé ọba ló ladé orí ìlẹ̀kẹ̀ ni ti àwọn ìjòyè Ní ìlú Oǹdó àwọn olóyè máa ń fi àkún sọ́wọ́ méjèèjì ṣùgbọ́n àwọn òpójí le fi sí ẹsẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ méjèèjì Ẹni tí kò bá jẹ oyè kò gbọdọ̀ fi àkún sí ọrùn tàbí ọwọ́ Bákan náà ẹni tí kò ní ìyàwó kò gbọdọ̀ jẹ oyè Gbogbo àwọn kókó tí a rí fàyọ yìí ni ó ṣe pàtàkì nínú oríkì orílẹ̀ àwọn ọba ìlú Oǹdó ORÍ KARÙNÚN ÀBÁLỌBÁBỌ̀ ÌFÁÀRÀ Bí ọkọ bá ròkun rọ̀ṣà èbúté ni yóò gúnlẹ̀ sí Orí tí ó gbẹ́yìn iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ni a dé báyìí Gbogbo ìlàkàkà wa lórí iṣẹ́ yìí àti àríwòye tí a ni tí ó jẹyọ ni yóò jẹ́ pàtó orí yìí A ó ṣe ìsọníṣókí àbájáde ìwádìí àmúyẹ àléébù àti ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ÌSỌNÍṢÓKÍ ÀBỌ́ ÌWÁDÌÍ Láti ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ni ó ti farahàn pé ipa àti ipò pàtàkì ni oríkì ń kó láwùjọ àwa ọmọ Yorùbá Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ṣe jẹ́ ìjánú ọmọ ni oríkì jẹ́ ìtọsẹ ọmọ ènìyàn Ìlú Oǹdó ti ó jẹ́ ọ̀kan lára ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ Oǹdó ni ó jẹ́ kókó àpilẹ̀kọ yìí Ọ̀pọ́ òye àti ìmọ̀ ni àpilẹ̀kọ yìí sì ti tún mú jáde nípa ìlú Oǹdó àti oríkì ọba wọn Lára àwọn ọgbọ́n àti ìmọ̀ tí a rí fàyọ nínú àpilẹ̀kọ yìí ni pé bí oríkì ṣe pàtàkì láàárín ìran Yorùbá bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe pàtàkì ní ìlú Oǹdó Èyí farahàn láti ara oríṣìí àwọn oríkì àdání àti oríkì àwọn ọba tí a bá pàdé nínú àpilẹ̀kọ yìí Lára àwọn ohun tí a bá pàdé nípa oríkì àwọn ọba yìí náà ni pé ó jẹ́ kí a mọ̀ wọn bí alágbára àti alákínkanjú ènìyàn Bákan náà ó tún ń ṣe àfihàn àwọn àṣà tí wọ́n gùn lé nípa pé wọn máa ń ní àánú àwọn ènìyàn lójú púpọ̀ A kò ṣàì rí ipò wọn nínú oríkì a rí i pé ìṣèlú wọn tó jẹyọ nínú oríkì wọn yìí náà ni pé wọ́n máa ń jẹ oyè mìíràn yàtọ̀ sí ọba Àfihàn oríkì àdáni tún jẹyọ nínú oríkì àwọn ọba wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá ṣe ní oríkì àdáni Yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àṣà yàtọ̀ sí èyí tí a ti mẹ́nu bà lókè ni ó tún jẹyọ nínú oríkì àwọn ọba wọ̀nyí tí a bá pàdé ÀMÚYẸ ÀTI ÀLÉÉBÙ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Pàtàkì ohun tí ó jẹ́ àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí yìí ni pé ó gbé àṣà àti ìṣe Yorùbá yọ Ó sì tún mú kí àwọn ohun tí ó ti ń dohun ìgbàgbé tún di àmúlò padà nílẹ̀ Yorùbá lápapọ̀ àti pàápàá ìlú Oǹdó bí àpẹẹrẹ a kì í ki oríkì mọ́ níbikíbi yálà níbi ayẹyẹ kan ni tàbí nínú ilé láti ṣe kóríyá fún ènìyàn Lọ́nà mìíràn ẹ̀wẹ̀ ó mu kí a ní ìmọ̀ àmọ̀dájú nípa ìlú Oǹdó tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìlú Oǹdó À mọ àṣà ìṣe èèwọ̀ iṣẹ́ àwọn babańlá wọn àti oríkì àwọn ọba wọn yàtọ̀ sí èyí a tún ní àǹfààní láti ní òye àti ìmọ̀ tó dájú nípa ètò òṣèlú àti ìṣèjọba lápapọ̀ àti pàápàá ètò ẹ̀sìn àti ètò wọn láti ibi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ àti ibi tí ó gbòòrò dé báyìí lónìí Láì ṣe àníàní bí a ṣe rí àmúyẹ nípa iṣẹ́ yìí náà ni a rí àléébù rẹ̀ Ọ̀kan lára àwọn àléébù náà ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn ni kò fi taratara dáhùn sí àwọn ìbéèrè tí a ń béèrè lọ́wọ́ wọn Bákan náà àwọn mìíràn rò pé ń ṣe ni a wá láti jí àwọn ohun ìṣúra wọn kó lọ nítorí ìdí èyí onírúurú wàhálà ìdààmú àti àbùkù ni wọ́n fi kàn wà kí á tó lè rí ìwádìí díẹ̀ ṣe fún iṣẹ́ ìwádìí yìí ÌMỌ̀RÀN FÚN IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Ohun tó dájú ni pé ọgbọ́n kò pin sí ibì kan Ibi tí ènìyàn bá ṣe é dé ni ó ń rí i mọ Ibi tí ènìyàn bá sì rí i mọ ni yóò sọ̀rọ̀ dé Ibi tí aṣèwádìí yìí bá a dé ni ṣíṣe àlàyé lórí oríkì àwọn ọba ìlú Oǹdó ṣùgbọ́n òye tí a tún ní ni pé ìwádìí lè dá lé ewì àbáláyé mìíràn bí i bọ̀lọ̀jọ́ àrùngbè tí ó lè fi kún ìmọ̀ wa nípa ìlú Oǹdó Yàtọ̀ sí èyí ààyè ìwádìí sì tún wá lórí oríkì àdáni àwọn ìdílé mìíràn tí wọ́n jẹ́ ìdílé olóyè yàtọ̀ sí ìdílé ọba ní ìlú Oǹdó ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ Láìṣe àníàní a ti ná ìgbárá a ti ná ìgboro lórí iṣẹ́ ìwádìí yìí ibi tí a bá dé rè é lórí àgbéyẹ̀wò oríkì àwọn ọba ìlú Oǹdó Ṣáká ló dájú bí àdá pé nínú oríkì àwọn ọba ìlú Oǹdó ni a ti rí gbogbo ohun tí àwọn ọba náà àti àwọn babańlá wọn ti gbé ṣe Kò sí júu jùu tí ẹnikẹ́ni fi lè boni lójú tí a bá ka oríkì wọn akínkanjú alágbára ni àwọn ọba tí ó ti jẹ ní ìlú Oǹdó ÀKÓJỌ ORÚKỌ ÌWÉ Adéoyè Orúkọ Yorùbá Ìbàdàn Adéoyè Àṣà àti Ìṣe Yorùbá Adéyẹmí L Tíọ́rì Lítíréṣọ̀ Ní Èdè Yorùbá Ìjẹ̀bú Òde Akinbinuade A Oríkì àti Ètò Ayé Ìlú Oǹdó Babalọlá Ìjálá Ìbàdàn Babalọlá A Orin Ọdẹ fún Àṣeyẹ Babalọlá A Àwọn Oríkì Orílẹ̀ Mẹ́tàdínlógún Babalọlá A Àwọn Oríkì Bọ̀rọ̀kìnní Dáramọ́lá O àti Jẹ́jẹ́ A Àwọn Àṣà àti Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá Ìbàdàn Oníbọnòjé Ládélé T àti Fáníyì JOO Ẹkún Ìyàwó Ìbàdàn Ògúnbọ̀wálé PO Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá Ìbàdàn Ọlábímtán A Àkójọpọ̀ Ìwádìí Ìjìnlẹ̀ Àṣà Yorùbá Àṣà Yorùbá Ìbàdàn Ọlátúnjí O Yorùbá Ògúnṣínà Yorùbá Ìlọrin Ṣówándé F àti Fágbèmí A Orúkọ Àmútọ̀runwá Ìbàdàn Yémiítàn O Ìjálá Aré Ọdẹ Ìbàdàn ÌṢỌWỌ́LOÈDÈ NÍNÚ ÌWÉ ERÉONÍTÀN ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀ TÍ LÁWUYÌ ÒGÚNNÍRAN KỌ ADENẸKAN ADEṢỌLA OLUWAFUNMILAYỌ APÁ KAN IṢẸ́ ÀṢEKÁGBÁ FÚN Ẹ̀KỌ́ ÀKÀGBOYÈ NÍNÚ ÌMỌ̀ ÌPÌLẸ̀ Ẹ̀DÁ Bii Eè NÍNÚ ÈDÈ YORÙBÁ NÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ YUNIFÁSÍTÌ ÌLỌRIN ÌLỌRIN NÀÌJÍRÍÀ OṢÙ ÈBÌBÌ ỌDÚN ÌFỌWỌ́SÍ Iṣẹ́ àkànṣe yìí ni a ti kà tí a sì rí i pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè àti Èdè Nàìjíríà Yunifásítì Ìlọrin Ìlọrin ALÀGBÀ LAYỌ̀ ÒGÚNLỌLÁ ỌJỌ́ ALÁBÒÓJÚTÓ OLÙYẸ̀WÒ ÌTA ỌJỌ́ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N ỌJỌ́ OLÓRÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁ ÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ÌFISỌRÍ Mo fi iṣẹ́ àkànṣe yìí sọrí bàbá tó bí mi lọ́mọ tí ó ti di olóògbé báyìí Àlàó Adénẹ́kàn ọmọ olódò ní Ìlàrẹ́ sùn un re Àmín Bákan náà màmá mi Olúbùkọ́lá Àbẹ̀ní Adénẹ́kàn ẹni tó ṣe gudugudu méje yààyà mẹ́fà lórí ẹ̀kọ́ mi Kí Ọlọ́run bá mi dá ẹ̀mí wọn sí kí wọn sì jẹun ọmọ pẹ́pẹ́pẹ́ Àmín ÌDÚPẸ́ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ẹni tí a ṣe lóore tí kò bá dúpẹ́ bí ọlọ́ṣà kóni lẹ́rù ni nítorí ìdí èyí ọpẹ́ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí; Ẹni àkọ́kọ́ ni Ọlọ́run ọba ọ̀gá ògo ọ̀gbàgbà tí í gba ẹni tirẹ̀ nínú ìṣòro ọba tó pa mí mọ́ tí kò jẹ́ kí ń rí ikú òjijì tí kò jẹ́ kí ń rí ìdádúró lẹ́nu ẹ̀kọ́ mi Olódùmarè ọpẹ́ ló yẹ fún orúkọ rẹ Bákan náà ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ alábòojútó iṣẹ́ àkànṣe yìí Alàgbà Layọ̀ Ògúnlọlá fún ìfaradà àti ìyànjú tí wọ́n ń gbà mí kí iṣẹ́ àkànṣe yìí tó di títẹ̀ ẹ ṣeun mo dúpẹ́ Ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ àwọn olùkọ́ mi gbogbo bí i; Ọ̀mọ̀wé Lérè Adéyẹmí Alàgbà Adéọ̀ṣun Aya Ọ̀gbẹ́ni Ọmọ́léwu O Aya Adékẹyè Alàgbà Báre Atóyèbí Alàgbà Òkèwándé àti àwọn olùkọ́ mi tó kù Ẹ ṣé púpọ̀ Olórí ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ màmá mi nítorí Yorùbá bọ̀ wọ́n ní àtiránmú gángan kò sẹ̀yìn èékánná Àwọn ni ọlọ́kọ̀ tó wà mí wá sáyé tí wọ́n tọ́jú mi láti kékeré títí di àkókò yìí Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé bàbá mi kò dúró ṣe baba ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àdúrà àti ooreọ̀fẹ́ Ọlọ́run màmá mi dúró gbọningbọnin lẹ́yìn mi wọ́n sì fi dámi lójú pé ibikíbi tí mo bá lè kàwé dé àwọn yóò rán mi nítorí ìdí èyí mo gbàdúrà pé iṣu ọmọ yóò jinná fún yin jẹ Àmín Síwájú sí i ìdúpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi Gbogboadé Adénẹ́kàn Adéwọlé Adénẹ́kàn Adérójú Adédàmọ́lá Adésẹwà Olúwasèyí aya Sàlámì Kíkẹ́lọmọ aya Adénẹ́kàn Ràmọ́tù aya Adénẹ́kàn Olúbẹ́nà Olúbùnmi Ọlámídé Allison ẹ ṣe é púpọ̀ iwájú ni ọ̀pá ẹ̀bìtì yín yóò máa ré sí Ibi gbogbo tí ire ayọ̀ yín bá wà Olódùmarè yóò jẹ́ kí ó tẹ̀ yín lọ́wọ́ Ní àfikún ń kò gbàgbé àwọn afẹ́nifẹ́re mi gbogbo bí i; Alàgbà Adédayọ̀ Adélékè Alàgbà Ayọ̀bámi Agbànà Dèjì Adébísí Ìbítọ́lá aya Ọlákànmí Ṣẹ́gun Bámidélé Ẹ ṣé púpọ̀ Ọlọ́run yóò tún ilé àti ọ̀nà yín ṣe o Àmín Bákan náà ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi gbogbo alábàáṣeré àti olùrànlọ́wọ́ mi gbogbo bí i Olówólayémọ̀ Ìrètíògo Onífádé Olúbùkọ́lá Sulaimon Balógun Olúfúnmibí Aṣagidigbi Òkìkíọlá Ajíbóyè Ẹ ṣé púpọ̀ Lákòótán mo dúpẹ́ lọ́wọ́ olólùfẹ́ mi fún ìfaradà ìnáwó nára ìforítì àbẹ̀wò àti ìfẹ́ tó fihàn nígbà gbogbo Ẹ ṣé púpọ̀ Ọlọ́run yóò nífẹ̀ẹ́ ẹ̀yin náà ÀṢAMỌ̀ Èròńgbà iṣẹ́ àkànṣe yìí ni láti fi pàtàkì ìlò èdè hàn ní àwùjọ Yorùbá nípa ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ìṣọwọ́loèdè òńkọ̀wé Láwuyì Ògúnníran Òdú ni òńkọ̀wé yìí láwùjọ Yorùbá Bẹ́ẹ̀ sì ni a kò lè kóyán rẹ̀ kéré nínú àwùjọ àwọn òńkọ̀wé alátinúdá ẹgbẹ́ rẹ̀ tó kù Iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò tú iṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò nípa ìṣọwọ́loèdè òńkọ̀wé Láwuyì Ògúnníran ÀTẸ ÀKÓÓNÚ Àkọlé Ìfọwọ́sí Ìfisọrí Ìdúpẹ́ Àṣamọ̀ Àtẹ Àkóónú ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Ìfáàrà Èrèdí iṣẹ́ ìwádìí Àńfààní iṣẹ́ ìwádìí Ibi tí ìwádìí gbòòrò dé Ọgbọ́n ìwádìí Ètò ìwádìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN Ìfáàrà Èdè Ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè Lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè Eréonítàn Tíọ́rì ìṣàmúlò Tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè ORÍ KẸ́TA ÀGBÉYẸ̀WÒ ERÉONÍTÀN ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀ Ìfáàrà Ìtàn ìgbésí ayé òńkọ̀wé Ìtàn inú Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Àwùjọ tó bí ìwé ìtàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Kókó inú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Ìlò Èdè nínú Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Àfiwé Ìfọ̀rọ̀dárà Àjùmọ̀rìn ọ̀rọ̀ Àwítúnwí Òwe Àkànlò Èdè Ọfọ̀ Orin Àríwísí ORÍ KẸ́RIN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ Ìfáàrà Ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí yìí Àmúyẹ àti àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí yìí Ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú Àkójọ orúkọ ìwé ORÍ KÌÍNÍ ÌPÌLẸ̀ ÌṢE ÌWÁDÌÍ ÌFÁÀRÀ Lítíréṣọ̀ ni aṣàfihàn ìgbé ayé àwùjọ kan Èdè ni èròjà tó ṣe pàtàkì jùlọ tí àwọn oníṣẹ́ lítíréṣọ̀ ń lò; tí a bá ka ìwé lítíréṣọ̀ kan tí a sí sọ pé o dun; dájúdájú èdè inú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ dún Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀ a jẹ́ pẹ́ a kò jayò pa Tí a bá ṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀nà tí oníṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ gbà lo èdè; èròńgbà ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ni láti jẹ́ kí a mọ ipa tí oníṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ kó nínú ìdàgbàsókè lítíréṣọ̀ àwùjọ rẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀nà ìmédèlò Ohun tí kókó iṣẹ́ yìí dálé ni wíwo ọ̀nà ìmédèlò òńkọ̀wé láwùjọ Ògúníran nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ A ó wo àmúyẹ àti àléébù rẹ̀ bákan náà ni a ó wo ipò tàbí ààyè òńkọ̀wé láàrín àwọn yòókù A pín iṣẹ́ yìí sí ọ̀nà mẹ́rin báyìí orí kìíní iṣẹ́ yìí ni a ti wo èrèdí iṣẹ́ ìwádìí àńfààní iṣẹ́ ìwádìí ibi tí ìwádìí gbòòrò dé ọgbọ́n ìwádìí àti ètò ìwádìí Orí kejì ni aáyan ọ̀mọ̀ràn A ó sọ̀rọ̀ nípa èdè ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè lítíréṣọ̀ àti eréonítàn tíọ́rì ìṣàmúlò Tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè Orí kẹ́ta ni a ti sọ̀rọ̀ nípa ọnà èdè tí òńkọ̀wé ṣàmúlò nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ ìtàn ìgbésí ayé òńkọ̀wé Àwùjọ tó bí ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ìlò èdè nínú Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ bí i; àfiwé ìfọ̀rọ̀dárà àjùmọ̀rìn ọ̀rọ̀ àwítúnwí òwe àkànlò èdè ọfọ̀ orin àti àríwísí Orí kẹ́rin iṣẹ́ yìí ni àgbálọgbábọ̀ ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí àti ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Ìdí pàtàkì tí a fi ń ṣiṣẹ́ ìwádìí yìí ni pé ọ̀pọ̀ ìwé ni Láwuyì Ògúnníran ti kọ bí i ewì ìtàn àròsọ àti eré onítàn ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ lámèyítọ́ sí ti wà lórí wọn ṣùgbọ́n kò tí sí ẹní tó ti sisẹ́ lórí ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ pàápàá jùlọ iṣẹ́ tó jẹ́ mọ́ ìmédèló òńkọ̀wé nínú ìwé náà Yàtọ̀ fún pé iṣẹ́ yìí yóò fi kún ìmọ̀ tó ti wà nílẹ̀ yóò túbọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí ipa tí ìlò èdè ń kó nínú iṣẹ́ ọ̀nà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ Ìdí mìíràn ni láti mọ bí Ògúníran ti ṣe pàtàkì tó láwùjọ àwọn òńkọ̀wé Yorùbá nítorí lónìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ló wà lórí àtẹ tí kò ní lárijà kan sànan Bákan náà àkíyèsí ti fihàn pé bí Ògúníran ṣe lọ èdè nínú Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ yàtọ̀ sí bí ó ṣe lọ nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ yòókù Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò tan ìmọ́lẹ̀ sí ìdí ti Láwuyì fi lo èdè lọ́nà tó yàtọ̀ báyìí ÀŃFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Àńfààní àkọ́kọ́ ni pé iṣẹ́ yìí yóò mú iṣẹ́ akadá gbòòrò lórí ìṣọwọ́loèdè àti lítíréṣọ̀ Yorùbá lápapọ̀ Bákan náà iṣẹ́ yìí yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀gùn fún àwọn tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn tí ó fẹ́ ṣe ìwádìí lórí ìlò èdè àwọn òńkọ̀wé ìsáájú Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò jẹ́ kí àwọn òńkọ̀wé mìíràn tí ó ń gbìyànjú tí wọn sì ń ṣe akitiyan láti gòkè ó lè máa ṣe àtúnṣe sí iṣẹ́ ti wọ́n náà Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò jẹ́ kí ìmọ̀ wa gbòòrò sí lórí ọnà tí Láwùyì Ògúníran ń gbà fi èdè ránṣẹ́ sí àwùjọ Síwájú sí iṣẹ́ yìí yóò jẹ́ kí a rí ìbáṣepọ̀ tó wà láàrín iṣẹ́ ọ̀nà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀dá èdè Èyí nìkan kọ́ iṣẹ́ yìí yóò tún jẹ́ kí a mọ bí òǹkọ̀wé oníṣe ọ̀nà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ ṣe ń ṣe àkójọ àwọn èròjà rẹ̀ lọ́nà tí àwọn èdè tí ó ń fi sí akópa kọ̀ọ̀kan lẹ́nu ti yóò fi ni nńkan se pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tó fi ń hàn sí àwùjọ IBI TÍ ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ Níwọ̀n ìgbà tó jé wí pé ìṣọwọ́loèdè nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ni à ń yẹ̀wò nínú ìwádìí yìí a ó ni ni àńfààní láti tenumọ́ àlàyé púpọ̀ lórí ẹ̀dá ìtàn àti ọ̀nà tó gbà ṣe ìfìwà wẹ̀dá dípò èyí ohun tí a ó ṣe ni pé a wo ọ̀nà tí Ògúníran gbà fi èdè sí àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ lẹ́nu a wo bóyà sítáì tó lò láti fi afọ̀ sí àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ lẹ́nu Bákan náà a ó ṣe àyẹ̀wò fínnífínní nípa onírúurú èdè tí òńkọ̀wé lò a ó sí wo ipa ti ìgbé ayé òńkọ̀wé kò nínú ọ̀nà tó gbà lọ èdè rẹ̀ Àwọn òńkọ̀wé ti wa sáájú Láwuyì Ògúníran àìmọye ló ti tún wà lẹ́yìn rẹ̀ niwòn ìgbà tí iṣẹ́ wa ò ti dálé àwọn tó wà sáájú àti àwọn tó wà lẹ́yìn rẹ̀ nńkan tí a ó ṣe ni pé kí a ṣe àfiwé òńkọ̀wé yìí ìyẹn Láwuyì Ògúníran pẹ̀lú àwọn òńkọ̀wé eré onítàn àsìkò rẹ̀ pàápàá wíwo ìlò èdè wọ́n ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ Onírúurú ọgbọ́n ìwádìí ni a ní nígbà tí a bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìwádìí lára wọn ni síse àmúlò àwọn èròjà bí lílọ yara ìkàwé ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò wíwo Jọ́nà àti wíwo oríṣiríṣi iṣẹ́ tó tí wà sáájú Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí a lọ ọgbọ́n ìwádìí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nípa lílo rédíò àti fọ́nrán láti gba ohun sílẹ̀ A sí tún lọ oríṣiríṣi ìwé tí àwọn onímọ̀ tí kọ̀ sáájú A lo ọgbọ́n ìwádìí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nítorí kí a lè gbọ́ òdodo lẹ́nu òńkọ̀wé nítorí Yorùbá bọ̀ wọn ni ẹnu òní kan láti gbọn pòún èyí ni pé tí a kò bá dé ọ̀dọ̀ òńkọ̀wé a kò lè mo ìdí tí o fi kọ̀wé rẹ̀ Kí a tó lọ sí ọ̀dọ̀ òńkọ̀wé a ti ṣe àtòjọ ìbéèrè wa sílẹ̀ a sí ti wa rédíò àti fọ́nrán láti fi gba ohun kalẹ̀ ṣùgbọ́n ó ṣe ni laanú wí pé orí àìsàn ni a ba abenọ ìmọ̀ wa ṣùgbọ́n o gbìyànjú nínú dídáhùn sí àwọn ìbéèrè wa Bákan náà ìwádìí tún gbé wa dé ìyàrá ìkàwé láti lọ wa àwọn ìwé tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ àti láti le fún wa ni ìmọ̀ kún ìmọ̀ ÈTÒ ÌWÁDÌÍ Yorùbá bọ̀ wọ́n ni àasá tí kò bá ni kanún kò le ṣe é di bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni iṣẹ́ ìwádìí tí kò bá ni ètò rí Ọ̀nà mẹ́rin ni a pín iṣẹ́ àkànṣe yìí sí ni orí kìíní àwọn ohun tí a máa gbé yẹ̀wò ni yìí a ṣe ìfáàrà a wo èrèdí iṣẹ́ ìwádìí àńfààní iṣẹ́ ìwádìí ibi tí ìwádìí gbòòrò dé ọgbọ́n ìwádìí àti ètò ìwádìí Orí kejì ni a ti sọ ohun tí èdè jẹ́ ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè lítíréṣọ̀ àti eréonítàn àti tíọ́rì ìṣàmúlò Orí kẹ́ta ni a ti ṣe àlàyé àwọn kókó inú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ìtàn inú ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ìtàn ìgbésí ayé òńkọ̀wé àwọn ọnà èdè tí òńkọ̀wé ṣàmúlò bí i; àfiwé àwítúnwí ọ̀rọ̀ àyálò àkànlò èdè ìbádọ́gba gbólóhùn òwe àti àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Bákan náà ni a tún ṣe lámèyítọ́ lórí àwọn ọnà èdè òńkọ̀wé pẹ̀lú Orí kẹ́rin ni a ti ṣe àkójọpọ̀ àbọ̀ ìwádìí ìmọ̀ràn fún àwùjọ a tún wo àléébù iṣẹ́ yìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN ÌFÁÀRÀ Lábẹ́ èyí a wo ohun tí àwọn asíwájú ti sọ nípa èdè nípa eré onítàn Yorùbá àti nípa ìmọ̀ ìsọ̀wọ́loèdè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ÈDÈ Èdè ni àhunpọ̀ ìró tí àwọn ẹ̀yà ènìyàn kan ń lò láti mú kí àṣọyé àti àgbọ́yé wà láàrín ara wọn Onírúurú ẹ̀yà ènìyàn ni ó wà bẹ́ẹ̀ agbègbè tí kálùkù ń gbé yàtọ̀ sí ara wọn Ìdí èyí àwọn ẹ̀yà ènìyàn kan náà tí ó ń gbé ni agbègbè kan náà ni ó lè lo èdè tí wọn gbọ́ tí wọn sì lè sọ fún ìbáṣepọ̀ àlàáfíà Oríṣiríṣi ènìyàn ni ó wà jákèjádò àgbáyé bí a tí rí àwọn aláwọ̀ funfun bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn aláwọ̀ dúdú wà Láàrín àwọn aláwọ̀ funfun ẹgbàà gbèje èdè ni ó wà bí a tí rí èdè faransé ni èdè Gẹ̀ẹ́sì Jámìní Látìnì Rósìá náà wà Bákan náà láàrín ènìyàn dúdú èdè pọ̀ lọ jara Bí i Haúsá Yorùbá Igbó Ẹdó ijọ́ọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ogún àwọn ènìyàn ni èdè èyí ti ó túmọ̀ sí wí pé ènìyàn nìkan ni Olódùmarè gbé èdè fúnun Gbogbo ohun abẹ̀mí ìyókù bí i ẹranko ẹyẹ àti ẹja kò ni èdè bí kò ṣe ariwo lásán Ènìyàn jẹ́ elédè nítorí wí pé ó ni àńfààní láti kọ́ èdè tí ó wù ún àti ní ìgbà tó wù ú Bákan náà èyí ni ó fi jẹ́ kí ó ṣe é ṣe fún ènìyàn láti gbọ́ àti láti sọ ju èdè kan lọ Ó wà lọ́wọ́ ìfẹ́ láti kọ́ èdè àti àńfààní láti lo oríṣiríṣi èdè fún àsọyé àti àgbọ́yé Fájẹ́nyọ́ sọ pé èdè ni ọ̀nà tí à ń gbà fi èrò wa hàn sí ayé gbọ́ Síwájú sí èdè ni ìró tí a sọ jáde láti ẹnu tàbí tí a kọ sílẹ̀ tí ó fi èrò ọ̀kan wa hàn ti o sì ní ètò tí ó sì ní ìtumọ̀ sí ẹní tí ó gbọ́ o tàbí tí ó ń kà á Fájényọ́ tẹ̀síwàjú pé àlàyé wa lórí ohun tí èdè túmọ̀ sí yìí fihàn pé ọmọ ènìyàn ni Ẹdùmàrè jogún èdè fún Èdè ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ wọn sí yàtọ̀ gédé gédé sí ti ẹ̀dá Ọlọ́run mìíràn bí i ẹyẹ ẹranko àti àwọn abẹ̀mí mìíràn Èdè ọmọnìyàn kún a sì lè lò ó láti fi ṣàlàyé gbogbo nńkan tí a ní lọ́kàn Ìdí nìyí tí a fi ń dá oríṣiríṣi àrà sí èdè wa yálà a ń kọ ọ́ sílẹ̀ ni tàbí a ń sọ ó lẹ́nu Adéyínkà òun náà fún èdè ni oríkì báyìí ó sọ pé Èdè ni à lè pé ni ìlànà tí ẹ̀yà ènìyàn kan ń gbà láti fi èrò inú wọn hàn yálà nípa kíkọ́ èrò náà sílẹ̀ tàbí nípa sísọ ó jáde lẹ́nu lọ́nà tí ó fi lè yé gbogbo ènìyàn tí ó ń lọ ìlànà náà Ajèlétí wo èdè bí i ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tí ó wà fún àsọyé láàrín àwọn ènìyàn àwùjọ kan Adéboyèjé rí èdè bí i ọ̀nà tàbí ìlànà kan tí àwọn ènìyàn gbá láti máa tẹ̀lé fi ronú kẹ́dùn yọ̀ tàbí ṣe àwọn nńkan mìíràn yálà nípa ọ̀rọ̀ sísọ tàbí ìwé kíkà lọ́nà tí o fi lè yé ẹní tí ó bá mọ ìlànà rẹ̀ ÌWÚLÒ ÈDÈ Nínú àlàyé tí a ṣe ni òkè a tí rí àrídájú pé ènìyàn nìkan ni Olódùmarè jogún èdè fún fún ìdí èyí a lè pé èdè ní Ògún àwùjọ ènìyàn kò sí ohun yòókù tí Ẹlẹ́dàá dá tí ó ni èdè bí kòṣe àmì lásán èyí tí kì í yípadà Èdè jẹ́ ohun tí a fi ń ronú tí a sí fi ń fi èrò inú wa hàn fún ẹlòmíràn yálà nípa sísọ ó jáde lẹ́nu tàbí kíkọ́ ó sílẹ̀ Yorùbá bọ̀ wọn ni ẹnu ẹní ni a fi ń sọ mi ò jẹ́ èyí ti ó fihàn pé ohun tí a rò nínú wa ni a fi èdè gbé jáde yálà ó wù wá ni o tàbí kò wù wá Èdè ni a fi ń kọ ọmọ ní ẹ̀kọ́ ilé àti ẹ̀kọ́ ìwé Èdè ni a fi ń ṣe ìròyìn yálà láàrín ara wa lórí rédíò tàbí tẹlifísàn Èdè ni a ń lò fún ìpolówó ọjà àti ìkéde gbogbo Èdè ni a ń ló níbi ayẹyẹ gbogbo yálà ayẹyẹ ìgbàyọ̀nda lẹ́nu iṣẹ́ tàbí àwọn àríyá gbogbo tó kù Lọ́rọ̀ kan èdè Yorùbá bí i àwọn èdè tí ó kù wúlò púpọ̀ nínú ẹ̀kọ́ ilé ìwà ọmọlúàbí ètò ìdárayá ètò ìlera ètò ọrọ̀ajé ìgbé àṣà ga níbi àwọn ayẹyẹ gbogbo ÌMỌ̀ ÌṢỌWỌ́LOÈDÈ ni orísun orúkọ fún ìmọ̀ yìí yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ àyálò láti inú èdè Gẹ̀ẹ́sì àti pé ó jẹ́ àkànpọ̀ ọ̀rọ̀ méjì Èyí ni Ìmọ̀ tí a pè ní yìí ni àwọn kan dábàá pé kí a máa pé ni Talitiiki Gẹ́gẹ́ bí èrò Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọlábíyi yai Ọ̀kanòjọ̀kan oríkì ni wọn fún un sé ohun tí ó kójú sí ẹnìkan lè kọ̀yìn sí ẹníkejì Ohun tí a lè fi ye pé ó fa sábàbí kò ju pé àwọn kan ń fi ojú ìmọ̀ ẹ̀dá èdè ṣe òdiwọ́n nígbà tí àwọn kan ń fi ojú ọ̀rọ̀ lámèétọ́ wò ó Ní wọ́n ìgbà tí òdiwọ́n ti yàtọ̀ dandan ni kí àgbékalẹ̀ náà yàtọ̀ Láti nńkan bí ọdún lẹ́yìn ogun àgbáyé kìíní ni àwọn ọmọ ilé Gíríkì ti ń kó ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ìsọ̀wọ́lọèdè A gbo pé onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan nínú ìwé rẹ̀ ni ó ti síso lójú eégún ìmọ̀ yìí èyí ni àwọn oníṣe ọ̀nà yòókù rí tí wọn fi ń ronú bí àwọn náà ṣe lè fi iṣẹ́ ọ̀nà wọn dásí ètò ìṣèlú kóówá wọn pàápàá ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ilé Rọ́síà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kí àbá tí kálùkù ń dá lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láwùjọ wọn ṣe àlàyé pé Ìmọ̀ ìsọ̀wọ́lọèdè ni nńkan ṣe pẹ̀lú àgbékalẹ̀ èrò tó ní ètò nínú ẹwẹ̀ ó tún ni nńkan ṣe pẹ̀lú oríṣiríṣi ọ̀nà tí a gbà láti yìí èrò yìí padà sí yálà ọ̀rọ̀ sísọ jáde lẹ́nu tàbí èyí tí a ṣe àkọsílẹ̀ síbẹ̀ àyípadà àwọn ohun èlò wònyìí sí ọ̀nà àgbàsọfọ̀ ni à lè pé ni ìmọ̀ ìsọ̀wọ́lọèdè Ohun tí ń sọ ni pé ìlànà àgbékalẹ̀ ètò èdè máa ń yàtọ̀ sí ara wọn Bí a bá sì fé ṣe àyípadà èyí máa ń jẹ́ àwòmọ́ ìmọ̀ọ́se ti ẹní kọ̀ọ̀kan ìtumọ̀ èyí ni pé ní wọ́n ìgbà ti ìrònú tàbí àgbékalẹ̀ kò papọ̀ ìṣọwọ́loèdè òjó gbọdọ̀ yàtọ̀ sí ti Aìná Èrò yìí kò yàtọ̀ púpọ̀ sí èrò; ìyapa tí òun ń sọ̀rọ̀ le ni ti ẹ̀yà lítíréṣọ̀ àti àbùdá àdání ti irúfẹ́ lítíréṣọ̀ bẹ́ẹ̀ ni Èyí nìkan kọ́ọ́ tún tọ́ka sí ìwà àdámọ̀ tó jẹ́ ti oníṣẹ́ ọnà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ń jẹyọ nínú iṣẹ́ rẹ̀ nígbà yòówù ti a bá ṣe àyẹ̀wò iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sọ pé Ìyapa tí oníṣẹ́ ọnà kọ̀ọ̀kan kúrò nínú òfin èdè nínú ààyè tó ní nígbà tó ń ṣe àgbékalẹ̀ èrò rẹ̀ Àwọn ìyapa wọ̀nyí a máa jẹyọ nínú ẹ̀ka èdè láti inú ẹ̀hun àwọn àbùdá tí àṣàyàn tí ń wáyé lójú ọ̀nà ìmédèlò Èrò ni pé a gbọdọ̀ le fọkàn sí irú ìyapa báyìí ni àìmọ̀ye ìgbà kí a tó lè sọ o pòún pé ìsọ̀wọ́lọ èdè bẹ́ẹ̀ ni yen Ààyè sì wa fún àsàfọ̀ kọ̀ọ̀kan iṣẹ́ òun jẹ sọ pé Ìṣọwọ́ ṣe tó mọ afọ̀ kan ni iṣẹ́ tí a rán tó sì ń jẹyọ lóòrè kóòrè àti ọ̀nà tí a lè gba máa ṣe àyípadà fún àwọn àbùdá èdè ní pàtàkì lọ́nà ti wọ́n fi yàtọ̀ sí àwọn àbùdá mìíràn nínú ẹ̀dá èdè Ìyapa kúrò nínú ìlànà tí ó ni bátànì tó wà ní ṣíṣeń tẹ̀lé ni gbogbo ọ̀nà ni ń tọ́ka sí tàbí ọ̀nà tí a lè gbà ránṣẹ́ nínú afọ̀ kan nípa síse àmúlò oríṣiríṣi àbùdá èdè lọ́nà tí ìtumọ̀ tàbí ìlò wọ́n yóò fi yàtọ̀ sí ìtumọ̀ wọn nínú ẹ̀dá èdè ó sọ èrò rẹ̀ ó gbà pé Ìmọ̀ ìsọ̀wọ́loèdè ni a ń lò láti gbé èrò ọ̀kan wa jáde sí olúgbọ́ Nígbà tí a bá mọ bí oníṣe ọ̀nà kan ṣe ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà tí ó fi yàtọ̀ sí iṣẹ́ mìíràn Èyí yóò fún wa ní òye láti mọ bí oníṣẹ́ ọnà bẹ́ẹ̀ ṣe pegedé sí nínú ìlò èdè Ohun tó ó jẹ ẹní yìí lógún ni pé kí a mo nípa ọ̀nà tàbí ara tí afẹ̀dèsọ́nà dá nígbà tó ń ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ sọ èrò rẹ̀ nípa ìmọ̀ ìsọ̀wọ́lọèdè ó gbà pé ìtumọ̀ yòówù tí a ó fún iṣẹ́ ọ̀nà àti ojú ti á ń rí kí a fi wó ó ara ìmọ̀ ẹ̀dá èdè ló ti wá Ó sọ pé Àwọn ti ìmọ̀ ìsọ̀wọ́lọèdè jẹ lógún ni àwọn tó ń ronú nípa èdè àti ìlò rẹ̀ Ní pàtàkì ohun ti ìmọ̀ ìsọ̀wọ́lọèdè ń fún ìkà mó ni pé báwo la ti ṣe ṣe àgbékalẹ̀ lítíréṣọ̀ ganan irú èyí tó wù kò jẹ́ èyí sì yàtọ̀ sí ohun tí a gbé kalẹ̀ ganan tí í ṣe lítíréṣọ̀ Èrò tí ń pé àkíyèsí wa sí ní pé nígbà tí a ba fẹ́ ṣe àtúpalẹ̀ a gbọdọ̀ wo ìlò ẹ̀hun ọ̀rọ̀ ìtumọ̀ wọ́n àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ nígbà tí a bá ń ṣe èyí a gbọdọ̀ lọ ìmọ̀ ẹ̀dá èdè LÍTÍRÉṢỌ̀ ÀTI ÌMỌ̀ ÌṢỌWỌ́LOÈDÈ Lítíréṣọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ àyálò tí a lò láti fi ṣàlàyé iṣẹ́ ọ̀nà tí a fi èdè ṣe Lítíréṣọ̀ jẹ́ awòjìji àṣà wa nítorí pé wọ́n ń fí àwọn ìwà ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ àti ìrírí àwùjọ wa hàn bí i wọn tí ń jẹyọ nínú iṣẹ́ wa ojoojúmọ́ Lítíréṣọ̀ Yorùbá jẹ́ àkójọpọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ tí a fi èdè Yorùbá gbé ka orí ìrírí ìwòye àti ìgbé ayé àwùjọ láti ìran kan de orí ìran kejì Lítíréṣọ̀ jẹ́ iṣẹ́ ọ̀nà tí ó dúró bí i díńgí tí a sì ń tí inú rẹ̀ wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwùjọ ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun èlò pàtàkì tí a lè fi ṣe àtúpalẹ̀ àwùjọ fún lítíréṣọ̀ ni oríkì bàyí Lítíréṣọ̀ ni àkọsílẹ̀ ti ó ṣe àlàyé àti ìgbé jáde èrò ìmọ̀lára àti ìhà tí a kọ sí ilé ayé Ọ̀pádọ̀tun sọ pé Lítíréṣọ̀ ni àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yálà tí a sọ lẹ́nu tàbí tí a kò sílẹ̀ ni èdè kan tàbí òmíràn láti fi ṣe àpèjúwe èrò ìmọ̀lára àti ìhùwàsí àwa ẹ̀dá nípa ilé ayé Tí a bá wá ń sọ̀rọ̀ nípa lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè èyí ni bí òńkọ̀wé alátinúdá ṣe dára sí ara iṣẹ́ ọnà rẹ̀ tàbí bí ó ṣe fi èdè dára nínú iṣẹ́ ọnà rẹ̀ tí ó ń ran sí àwùjọ sọ pé Ìṣọwọ́loèdè ni ṣíṣe àyẹ̀wò afọ̀ ajẹmọ́ lítíréṣọ̀ pẹ̀lú èdè pé òun àkọ́kọ́ nínú ìtúpalẹ̀ àti kíka iṣẹ́ lítíréṣọ̀ gbọdọ̀ tẹ̀lé ìgbésẹ̀ inú ìmọ̀ ẹ̀dá èdè Òun àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì jù sí wa nínú kíka lítíréṣọ̀ ni èdè inú rẹ̀ òńkọ̀wé lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè Àwọn òńkọ̀wé lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè wa dúró bí afojúunúsọ́nà wọ́n dúró bí aríran àti alásọtẹ́lẹ̀ Èyí ló máa ń mú kí lítíréṣọ̀ bá ojú ayé mú ni gbogbo ìgbà Òńkọ̀wé alátinúdá ni ẹní tí ń fi èdè ṣe ọ̀nà ẹní tí ó ń fi ojú inú wo ilé ayé ẹní tí ń fi àròjinlẹ̀ kọ èrò rẹ̀ sílẹ̀; èyí tí ó lè jasi ewì ìtàn àròsọ tàbí eréoníṣe Iṣẹ́ ọnà tí òńkọ̀wé alátinúdá ń ṣe yìí lè sun jáde láti inú ìrírí ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ àṣà àti iṣẹ́ inú àwùjọ tí òńkọ̀wé wà Àwọn nńkan wòn yìí sí ni èròjà tí òńkọ̀wé alátinúdá máa ń bùlò bí òní òjò fún àṣeyorí iṣẹ́ ọnà rẹ̀; iṣẹ́ ọ̀nà tí òńkọ̀wé ṣe yìí ni a ń pé ní lítíréṣọ̀ Bákan náà ni òrìṣà kan wà tí ó máa ń gun àwọn òńkọ̀wé alátinúdá Èyí ni Akínwùmí Ìṣọ̀lá pé ní òrìṣà tí ń gún òńkọ̀wé Ṣùgbọ́n òrìṣà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó máa ń gún àwọn òńkọ̀wé alátinúdá òrìṣà kí nńkan ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá máa jọba ni ó gun Láwuyì Ògúnníran òrìṣà ìdẹ́kun ìwà ọ̀daràn ló gún Kọ́lá Akínlàdé àti Ọládẹ̀jọ Òkédìjí Òrìṣà kí nńkan ìṣẹ̀ńbáyé àti àṣà Yorùbá má parẹ́ ni ó gún Dúró Ládipọ̀ Òńkọ̀wé lítíréṣọ̀ àti onímọ̀ ìṣọwọ́loèdè gbọdọ̀ jẹ́ ẹní tí ó ni ẹ̀bùn àti ìmọ̀ tó jinlẹ̀ tí ó sí gbòòrò nípa bí a ṣe lè lo ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ òwe àti àkànlò èdè ni ọ̀nà tí ó wuyì ni ọ̀nà tí ó lè múṣẹ́ òńkọ̀wé alátinúdá di àkàtúnkà Bákan náà ni pé òńkọ̀wé lítíréṣọ̀ àti onímọ̀ ìṣọwọ́loèdè gbọdọ̀ jẹ́ ẹní tí ó ni ìmọ̀ nípa àṣà ẹ̀sìn àti iṣẹ́ àwa Yorùbá nítorí láti inú wọn ni yóò tí máa ṣe àmúlò èròjà fún iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀ ERÉONÍTÀN Láàrín àwọn Yorùbá oríṣiríṣi eré ni ó wà Bí erémọdé ṣe wà ni eré ayò ọlọ́pọ́n wà; eré orin ìlù àti ijó náà wà pẹ̀lú Bí ènìyàn méjì bá jọ ń dá àpárá tàbí tí wọ́n ń ṣe àwàda eré náà ni wọn yóò sọ pé wọ́n ń ṣe Ó yẹ kí a kíyèsí wí pé ìtumọ̀ tí ó gbòòrò tí eré ni yìí kan náà ni ní nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì Nígbà tí wọ́n bá lọ ni Gẹ̀ẹ́sì láti fi tọ́ka sí eré tí a fi gbé ìtàn kalẹ̀ ó yẹ kí a mọ̀ pé àmúlò ọ̀rọ̀ náà lọ́nà ọ̀tọ̀ ni Kí àmúlò yìí ba yàtọ̀ gédégédé sí àmúlò ti gbogbo gbòò ni àwọn onímọ̀ tí ó túmọ̀ rẹ̀ sí Yorùbá fi sọ onítàn pọ̀ mọ́ eré láti túmọ̀ gẹ́gẹ́ bí eré tí ó ni tian nínú tàbí tí a fi hun ìtàn pọ̀eré onítàn Láti inú ọ̀rọ̀ Gírìíkì ni Gẹ̀ẹ́sì pàápàá ti yá drama lò Ìtumọ̀ rẹ̀ nínú èdè gírìíkì sí ni iṣẹ́ Ìdí nìyí tí a fi lọ eré oníṣe láti túmọ̀ drama sí Yorùbá Ó yẹ kí a tọ́ka sí i wí pé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ èdè ìperí méjèèjì yìí gbẹ́nulẹ́nu tàbí pé wọ́n wọnú ara wọn Kò sí eré onítàn ti kò ni iṣẹ́ nínú Nípa ẹ̀dá ènìyàn ni àwọn ìtàn náà máa ń dálé àtòjọ iṣẹ́ àwọn ènìyàn ni sì í máa di ìtàn Ìdí nìyí tí gbogbo eréonítàn fi jẹ́ eréoníṣe Adédèji pé eréoníṣe ni iṣẹ́ ìsìnnijẹ tí a ṣẹ̀dá tí ó ni àsepọ̀ pẹ̀lú àṣà ẹ̀sìn àti èdè àwọn ènìyàn kan Oyèkàn Owómóyèlá náà kí eréoníṣe gẹ́gẹ́ bí Eré tí à ń ṣe ni àkókò kan ti àwọn ènìyàn méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ń sin àwọn kan jẹ́ nínú afọ̀ kan tí a gbé kalẹ̀ tí àwọn aṣafọ̀ kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ìtàn sí kópa nínú rẹ̀ ni èrò àti fi da àwọn òńwòran lára yá lórí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ Kókó pàtàkì ti oríkì yìí ń tọ́ka sí ni pé òṣèré gbọdọ̀ wà kí òńwòran sí wà bẹ́ẹ̀ ni ṣùgbọ́n a lòdì sí wí pé dandan ni kí eré dá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tí ṣẹlẹ̀ rí Ni èrò ti Ọlá Ròtìmí sọ pé Eréoníṣe jẹ́ ìsìnjẹ iṣẹ́ kan tàbí ìsìn jẹ tí èèyàn kan Ó sì lè jẹ́ tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn tí a gbé kalẹ̀ láti fi dá àwọn òńwòran lára yá Oríkì yìí tọ́ka sí èròńgbà ìsìnjẹ láti dá òńwòran lára yá a gbọdọ̀ rántí pé ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àti ìkọ́nilédé náà wa lára èròńgbà eréoníṣe pàápàá ni àwùjọ tiwa TÍỌ́RÌ ÌṢÀMÚLÒ Kí a tó mẹ́nu ba irú tíọ́rì tí a fẹ́ ṣàmúlò ó yẹ kí a sọ ohun ti tíọ́rì jẹ́ ni ṣókí Adéyẹmí kí tíọ́rì báyìí Tíọ́rì dàbí abẹfẹ́lẹ́ ìmọ̀ tí a fi ń la ìfun àti ẹ̀dọ̀ iṣẹ́ kan Tíọ́rì ni ìlànà kan tí ó jẹ jáde láti inú ìrònújinlẹ̀ tí a kà sí òótọ́ lẹ́yìn tí a dán an wò tí o sì jẹ́ òótọ́ bákan náà Oríṣiríṣi tíọ́rì ni ó wà fún ṣíṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ Lára wọ́n ni tíọ́rì ìfojúìhun wò ìhun inú iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ló ṣe pàtàkì sí àwọn agbọ̀ràn dún tíọ́rì yìí tíọ́rì ìfojú ààtòwò ohun to jẹ tíọ́rì yìí lógún jù ni iṣẹ́ ọnà inú ìwé kan Tíọ́rì ìṣègbèfábo èyí ni tíọ́rì tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí ìjẹgàbalé àwọn ọkùnrin lórí àwọn obìnrin Tíọ́rì ìfojú ìtànìgbésí ayé òńkọ̀wé wò ohun tí tíọ́rì ń sọ ni pé kí a tó lè ṣe ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ kan a gbọdọ̀ mo irú ìtàn ìgbésí ayé òńkọ̀wé bẹ́ẹ̀ Tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè ohun tí tíọ́rì yìí máa ń wò ni ọ̀nà tí òńkọ̀wé gbà lọ èdè nínú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó fi yàtọ̀ sí ti ẹlòmíràn Tíọ́rì tí a fẹ́ ṣe àmúlò nínú iṣẹ́ àkànṣe yìí ni tíọ́rì ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ìṣọwọ́loèdè ni àwọn agbátẹrù tíọ́rì yìí máa ń wò gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ sáájú ìṣọwọ́loèdè òńkọ̀wé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ni a sì fẹ́ wò pẹ̀lú Èyí ló mú wa yan tíọ́rì yìí láàyò ORÍ KẸ́TA ÀGBÉYẸ̀WÒ ERÉONÍTÀN ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀ ÌFÁÀRÀ Ní abala yìí ni a ó ti wo ìtàn ìgbésí ayé òńkọ̀wé ìtàn inú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ìlò èdè òńkọ̀wé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ ÒŃKỌ̀WÉ A bí Láwuyì Ògúnníran ní oṣù kọ́kànlá ọdún ní ìlú Ìbàdàn Abúlé Akínkúnmi ni ìlú Ìrókò ní ìjọba ìbílẹ̀ Akínyẹlá lẹ́bàá Ìbàdàn ni oko wọn Orúkọ bàbá rẹ̀ ni Alàgbà Àmọ̀ó Ògúnníran Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Arábìnrin Julianah Oyèrónkẹ́ aya Ògúnníran Agboilé Arógunmásàá ní ìlú Ìbàdàn ni agboilé rẹ̀ Ẹlẹ́sìn Kírísítì ní í ṣe Ìran bàbá rẹ̀ ni ó sì máa ń jẹ Baṣọ̀run ti ìlú Ọ̀yọ́ Òrìṣà Ògún ni wọ́n ń bọ ní ìdílé Láwuyì Ògúnníran ògún ló ṣẹ́ wọ́n sílẹ̀ wọn kì í ṣe alágbẹ̀dẹ ọmọ ògún ganan ni wọ́n Gẹ́gẹ́ bí kò ti sí ọmọ Yorùbá tí kò ní oríkì ìdílé tirẹ̀ ni Mòso wọ́n máa ń kì í ní; Àyìndé ògún Ọmọ olóògun mòso Ọmọ Awoyaakin Ó bẹ̀rẹ̀ iléìwé nígbà tí ó di ọmọ ọdún mẹ́sànán ní iléìwé ti ní ìlú Ìrókò Ó tún lọ sí iléìwé Fìdítì Ó ṣe ìdánwò oníwèé mẹ́fà ó sì yege Ó sì ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ Lọ́yà kan ní Èkó gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé Ó gba oyè nínú iṣẹ́ ìròyìn ó tún di olóòtú àgbà nínú iléiṣẹ́ ìwé ìròyìn Ìmọ́lẹ̀ Òwúrọ̀ gẹ́gẹ́ agbàròyìn Láwuyì Ògúnníran tún ṣiṣẹ́ ní ìlú Èkìtì àti Iléṣà tí ó fún un ní àńfààní láti mọ àwọn ìlú wọ̀nyí Ìyàwó kan ni ó ní ó sì jẹ́ àgbà ọ̀jẹ̀ níbi iṣẹ́ ìwé ìròyìn Ohun tó jẹ Láwuyì Ògúnníran lógún tí ó fi ń kọ ìwé ni pé láti iléìwé alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ ni ó ti máa ń ka àwọn ìwé Aláwìíyé tí olóògbé J F Ọdúnjọ kọ àti àwọn ìwé olóògbé Fágúnwà Àwọn ìwé tí ó kà yìí ni ó ṣe okùnfà ohun tó ó jẹ ẹ́ lógún tí ó fi kọ̀wé Ó tún máa ń sín àwọn Eégún Aláré jẹ tí wọ́n bá ń pe ẹ̀sà èyí ló fà á tí ìwé rẹ̀ Eégún Aláré fi dá lórí ẹ̀sà Ìwé àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ kọ dá lórí Ìtàn bí òṣùpá ṣe lọ sọ́run ìwé yìí jáde ní iléiṣẹ́ atẹ̀wé Àwọn ìwé rẹ̀ tó wà lórí àtẹ báyìí ni; Eégún Aláré Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Àtàrí Àjànàkú Ọ̀nà kan Ò Wọjà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ àwọn ìwé tí Láwuyì Ògúnníran kọ ń yí àwùjọ padà nípa jíjẹ́ iṣẹ́ tí ó rán wọn Ó kópa pàtàkì láti mú kí ìdàgbàsókè bá èdè Yorùbá Ó wà lára àwọn olùpilẹṣẹ̀ Ó tún wà lára àwọn tó gbé ìwé Yorùbá jáde Láwuyì Ògúnníran ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òńkọ̀wé mìíràn wọ́n sì jọ pa ọwọ́ pọ̀ kọ àwọn ìwé lóríṣìíríṣìí bí i; Ewì Ìwòyí ÌTÀN INÚ ÌWÉ ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀ Eréoníṣe ajẹmọ́tàn ni ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Ìtàn tí ó hàn dé jùlọ nínú rẹ̀ ni bí Òwú Yìngbìn tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí a kọ́kọ́ tẹ̀dó lẹ́yìn odi IléIfẹ̀ ṣe tú àti ipa tí àwọn ẹ̀yà Yorùbá kọ̀ọ̀kan bí Ìjẹ̀bú Ifẹ̀ Ẹ̀gbá àti Ọ̀yọ́ kó nínú pípa ìlú náà run Bákan náà ni a gbọ́ nípa bí ilẹ̀ Aláàfin Ọ̀yọ́ ṣe tú tí àwọn ìlú tó fi ń somi ara sì jàbọ́ kúrò tí òun náà sì di aláì lágbára Nínú ìtàn yìí ni a ti rí iṣẹ́ tí Ẹ̀yìnlààrò rán sí àwùjọ ọmọ Oòduà Nínú eré Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ a rí i kà wí pé lẹ́yìn ikú Abíọ́dún Aláàfin Ọ̀yọ́ pàápàá jùlọ láyé Aólẹ̀ òwò ẹrú tún bẹ̀rẹ̀ padà ní pẹrẹwu ní IléIfẹ̀ àti agbègbè rẹ̀ àwọn Ìjẹ̀bú ni wọn sì ń ra ẹrú tí wọn sì ń tà wọ́n fún àwọn Òyìnbó Ọ̀rọ̀ òwò ẹrú tó ń gogò sí i yìí ló mú kí Olúkòyí fún Olówu àti Olúkùewu wá jíṣẹ́ Aólẹ̀ fún olówu tí ó sì rò ó wí pé kí ó mú òpin dé bá òwò ẹrú ṣíṣe Báyìí ni Òwu gbógun ti àwọn ìlú abẹ́ Ifẹ̀ ní Apòmù tí ó jẹ́ ọjà ńlá fún òwò ẹrú Owó tí Òwu gbé yìí ló mú kí Ifẹ̀ sígun ìdí ògùngun tí Òwu sì pa àwọn Ifẹ̀ ní ìpakúpa Ìjà yìí àti ìjà gboro tó wáyé láàárín Òwu pẹ̀lú Ìjẹ̀bú lọ́jà Apòmù ni ó fa kí Àpapọ̀ ogun Ìjẹ̀bú àti Ifẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìsàńsá Ọ̀yọ́ àti Ẹ̀gbá gbógun ti Òwu tí wọ́n sì pa Òwu Yìngbìn run Lẹ́yìn ìgbà tí ogun Òwu parí tán àlàáfíà kò padà sáàrin àwọn Yorùbá Gbogbo ayé di sánbẹsùn fapórọrí Wọ́n ń dira ogun láìsí ogun nítorí ìdágìrì ìjà Àwọn Yorùbá apá ìlà Oòrùn bí i; Ìjẹ̀ṣà Èkìtì Àkókó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ gbé ìránṣẹ́ àlàáfíà dìde láti bá àwọn tó ń jà parí ìjà kí àlàáfíà sì padà wá jọba láàárín wọn Àsìkò yìí náà ni Odùduwà yíra padà sí Ẹ̀yìnlàárò Ó kó àwọn aṣojú àwọn tí wọn lọ́wọ́ nínú ogun náà jọ Ó fi àṣìṣe ẹnìkọ̀ọ̀kan hàn án Èyí tí ó ga jùlọ nínú àwọn àṣìṣe yìí ni àìro ẹ̀yìn ọ̀rọ̀ wò ìmọtara ẹni nìkan àti àìrántí alájọbí tí ó jẹ́ baba wọn Bákan náà ni ó dá Adégbàremú tí ó jẹ́ aṣojú Yorùbá Ìlà Oòrùn lẹ́bi nítorí wí pé àwọn tí ó sojú fún tí gba àwọn àjòjì gòdògbò láàyè láti máa jọba lórí ilẹ̀ Oòduà Gbogbo àwọn aṣojú wọ̀nyí gba ẹ̀bi wọn nígbẹ̀yìn wọ́n sì gbà wí pé ilé ọlá Oòduà tí àwọn ti fọwọ́ ara àwọn wú àwọn gbọdọ̀ tún un mọ nítorí kí ọmọ Yorùbá tó tí jẹ́ ọmọ alátẹ ìlẹ̀kẹ̀ tẹ́lẹ̀ àti ọmọ alátẹ àkún máa ba à di ọmọ alátẹ ọ̀rúnlá ÀWÙJỌ TÓ BÍ ÌWÉ ERÉONÍTÀN ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀ Láàárín ọdún sí kí a tó gba òmìnira ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà abẹ́ ìjọba Òyìnbó ni Nàìjíríà wà nígbà náà Ètò ọrọ̀ajé àti òṣèlú àti ètò ìbáraẹnigbépọ̀ nígbà náà farajọ ti àwọn Òyìnbó Ṣùgbọ́n ní ọdún tí ìjọba kúrò lọ́wọ́ àwọn Gẹ̀ẹ́sì tí ó di tí àwa ara wa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nńkan ni àyípadà ti dé bá ní orílẹ̀èdè Ní ọdún ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ nígbà náà ni ó ṣokùnfà kíkọ ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Kí àwọn ìran Yorùbá lè dẹ́kun ọ̀tẹ̀ àti ìjà àárín ara wọn àti fífi òpin sí òwò ẹrú ṣíṣe láwùjọ ló bí ìwé yìí Ní ọdún tí òńkọ̀wé kọ ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ètò òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá burú jáì oníkálùkù àwọn ọba ìlú wọ̀nyí ló ń fẹ́ agbára àti orúkọ Ní ọdún yìí ayé ti yípadà àsìkò yìí ni àwọn Òyìnbó amúnisìn wọ ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n sì ń ra ọmọ ènìyàn bí ẹrú ọmọ aráyé wá di mímú so bí ẹran ọmọ ìyá méjì wá ń dọdẹ ara wọn nítorí àtilà nídìí òwò ẹrú Ṣe ọmọ iná là á rán síná ni àwọn Òyìnbó tó ń ra ẹrú fi ọ̀rọ̀ náà ṣe Àwọn ọmọ Yorùbá ni àwọn olówò ẹrú tún bẹ̀ lọ́wẹ̀ láti máa bá wọn jí ènìyàn gbé Àwọn Yorùbá fààyè gba ohun tí kò tọ́ wọn wa ń gbógun tira wọn Wọ́n fi àìnísùúrù wólé ọlá wọ́n sọ ilẹ̀ tí ó yẹ kí ó kún fún oyin àti wàrà wọ́n sọ ọ́ di ilẹ̀ tó ń sàn fún ẹ̀jẹ̀ Wọ́n wà sọ àtẹ ìlẹ̀kẹ̀ wọn di àtẹ ọ̀rúnlá Ọ̀yọ́ ń yọ gbogbo ọmọ ìyá rẹ̀ sílẹ̀ Òwu ò wu mọ́ Kúrunmi di kékeré a rí àpẹẹrẹ nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Ogun ti tu Òwu àwọn tó fọ́lá Òwu pinnu láti má ṣe jẹ́ kí wọ́n tún Òwu kọ́ mọ́ àti láti gbẹ̀san lára àwọn ìlú tó ran Òwu lọ́wọ́ nínú ogun náà Wọ́n tú Ìkijà wọ́n tú Erunmi tí í ṣe ìlú abẹ́ Òwu tí Olówu sá lọ oi Ní àkótán kí àlàáfíà lè jọba ní ilẹ̀ Yorùbá àti kí ìfẹ́ le wà láàárín àwùjọ ni òńkọ̀wé fifi ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ pàrokò sí gbogbo ọmọ ilẹ̀ Yorùbá káríayé pé kí ìṣọ̀kan jọba láàárín àwọn Yorùbá KÓKÓ INÚ ÌWÉ ERÉONÍTÀN ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀ Àwọn kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì tí a fẹ́ yẹ̀wò nínú eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ni ìjẹgàbalé ètò ọrọ̀ajé ètò òṣèlú ààbò ìlú ẹ̀sìn àwọn Yorùbá ìpè fún ìpadà ìṣọ̀kan ÌJẸGÀBALÉ Èyí ni kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì tí àwọn kókó mìíràn ṣo mọ́ A lè sọ wí pé òun ni ó kó àwọn yòókù sòdí nínú ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Ìjẹgàbalé ló lè fa kí a máa mú ọmọ ẹlòmíràn tà lẹ́rú láti lè mú kí ètò ọrọ̀ajé tẹni gbéra sọ Ìjẹgàbalé ló mú kí aṣáájú gbẹ́sẹ̀ lé ìyàwó àṣẹ̀ṣẹ̀gbé tí wọn ń lọ mú fún ọkọ rẹ̀ lọ́fà Aṣáájú sọ̀rọ̀ ó ní; Ìgbà yìí lo tó sehun ti mo fẹ́ fún mi Omífisáyọ̀! Wá mú obìnrin yìí lọ sílé fún mi ó ti dìyàwó mi ní tirẹ̀ ayé kan kò le yẹ̀ẹ́ oi Bí kò bá sí ti ìjẹgàbalé ẹ̀yà kan kò ní máa gbógun tí ẹ̀yà mìíràn débi wí pé wọn a pa ìlú náà run Gẹ́gẹ́ bí àpapọ̀ ogun Ìjẹ̀bú pẹ̀lú Ifẹ̀ àti àwọn tí wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ ṣe pa Òwu yìngbìn run Èyí náà ló fa kí ìlú tí ó jẹ́ alàgàta bí Ìwó fọgbọ́n fara mọ́ Ifẹ̀ dípò kí wọn dóòlà ìjà náà Ẹ̀rù tó jọ pé ó ń ba Ìwó ni pé tí Òwu bá ṣẹ́gun Ifẹ̀ tán ewu ńlá ni fún Ìwó Èyí ìjẹgàbalé náà ló fa kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan máa gbìyànjú àròjàre níwájú Ẹ̀yìnlàárò ÈTÒ ỌRỌ̀AJÉ Ètò ọrọ̀ajé ló mú àwọn ọmọ Odùduwà gbógun tira wọn títí wọ́n fi dojú Òwu bolẹ̀ Lára àwọn ẹ̀ka ètò ọrọ̀ajé tó fa sábàbí ni òwò ẹrú ṣíṣe Àwọn Ifẹ̀ ń mú àwọn Ọ̀yọ́ lẹ́rú Wọ́n ń tà wọ́n fún àwọn Ìjẹ̀bú tí wọ́n a tún wọn tà fún àwọn Òyìnbó Mẹ́ta mẹ́ta bí iṣu ni wọn ń lé ènìyàn tà lọ́jà Apòmù Àwọn mẹ́rúmẹ́rú tilẹ̀ tún ń gba owó àgbà sílẹ̀ tí ó mú un di dandan fún wọn láti wá ẹni mú kí wọ́n ba à lè fi dí àgbàálẹ̀ tí wọn ti gbà lọ́wọ́ àwọn aláròóbọ̀ ẹrú A rí àpẹẹrẹ nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ nígbà tí aṣáájú àti Okúnnọ́wọ̀ ń dúnàdúrà lọ́wọ́ ara wọn tí Okúnnọ́wọ̀ sì wí pé; Ó dá a mo faramọ́ ọn Só o mọ̀ pé o ti gbàgbàsílẹ̀ níjẹta? oi Òwò ẹrú tí wọn ń ṣe lọ́jà Apòmù ló kógun Òwu ja Apòmù àti ogun Òwu bá àwọn ìlú wọ̀nyí jẹ́ ló mú kí Ifẹ̀ ṣígun láti gbẹ̀san A lè tànmọ́ọ̀n pé èrò láti dáàbò bo òwò ẹrú ló mú Ifẹ̀ ṣígun láti gbẹ̀san Èrò yìí kan náà kò ní sàìwà lọ́kàn Ìjẹ̀bú nígbà tí àpapọ̀ ogun Ìjẹ̀bú àti Ifẹ̀ dìde sí Òwu nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Ó tilẹ̀ hàn wí pé àwọn àgbà ìjòyè Ìjẹ̀bú kan kò tún fara mọ́ ogun náà nítorí pé yóò dí ètò ọrọ̀ajé Ìjẹ̀bú lọ́wọ́ ní ọjà Apòmù A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Olówólayémọ̀ sọ pé; Mo fi lọ wọn ọ̀pọ̀ wọ́n ló sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà búburú gbáà ni Òwu hù sí Ìjẹ̀bú lọ́jà Apòmù lọ́jọ́ ìjà búburú náà Ṣùgbọ́n kí a má ṣe ba wọn jà kí a ba a le máa ní àńfààní níná ọjà Apòmù lọ títí Ṣùgbọ́n àwa díẹ̀ kò fara mọ́ èyí pẹ̀lú èrò pé bí a kò bá jà ti a wa ń bẹ Òwu kí ó jẹ́ ka le máa nájà Apòmù èébú tí taja tẹran ó máa bú wa ni pé a fẹ́ràn òwò ju ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn wa táwọn Òwu pa lọ́jà Apòmù oi Ètò ọrọ̀ajé tó dá lórí òwò ẹrú yìí náà ni a lè sọ pé ó mú kí àwọn Ifẹ̀ àti Ìjẹ̀bú tí wọn faramọ́ òwo náà rí ìbọn àti ẹ̀tù gbà lọ́wọ́ Òyìnbó tí àwọn ọmọ Oòduà sì bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó láti ṣekú para wọn títí wọ́n fi tú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú bí Òwu àti Ìkijà Tí a bá tún wò ó a ó rí i pé ètò ọrọ̀ajé náà ló fa ìjà gboro tó bẹ́ sílẹ̀ láàrín Ìjẹ̀bú àti Òwu lọ́jà Apòmù Ọkùnrin Òwu kan ra ataare ogójì lọ́wọ́ obìnrin Ìjẹ̀bú dípò kí ọkùnrin yìí bá ataare dín ẹyọ kan ṣoṣo Èyí ló fa gbọ́misí iomiòtóo ibi tí wọn ti ń gbìyànjú àti pẹ̀tù sọ̀rọ̀ ni ọmọ Akọgun Òwu ti wọ̀ sáàrín wọn tí ó sì da igbá iyọ̀ Ìjẹ̀bú mìíràn nù lọ́jà Apòmù Èyí ló túbọ̀ mú kí ìjà búrẹ́kẹ Ọ̀pọ̀ Ìjẹ̀bú ló bá ìjà igboro náà lọ Ẹ̀san ìjà gboro tó ṣẹlẹ̀ ní Apòmù yìí ni Ìjẹ̀bú sọ pé àwọn ń gbà nínú ogun tí àwọn pẹ̀lú Ifẹ̀ fi pa Òwu run A ti rí i báyìí wí pé ipa ńlá ni ètò ọrọ̀ajé kó nínú ogun tí àwọn Odùduwà gbé ti ara wọn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ÈTÒ ÒṢÈLÚ Nínú ìwé eréonítàn yìí a rí Òwu tó ń ja àwọn ìlú mìíràn lábẹ́ Ifẹ̀ àti Ifẹ̀ pàápàá lógun Ète wọn ni láti da wàrìwàrì bo ìlú tó yí wọn ká kí wọ́n ba à lè dẹni ìwárí fún Bákan náà ni ó jẹ́ pé ọ̀nà láti dá àwọn ìlú abẹ́ Ifẹ̀ lọ́kàn le ni ogun àkókò tí Ifẹ̀ gbé ti Òwu Àsìkò yìí náà ni Ọ̀yọ́ di aláìlágbára nítorí pé gbogbo àwọn ìlú ńlá ńlá tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ ń yalọ láti lè wá òmìnira ara wọn kí wọn sì bọ́ lọ́wọ́ líle tí Aólẹ̀ fi ń mú wọn Ohun tí a kà nínú Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ni wí pé Pópó Kétu àti Ìlọrin tí bọ́ lọ́wọ́ Ọ̀yọ́ Bákan náà sì ni àwọn obìnrin Ọ̀yọ́ dira ogun wọ́n fẹ̀hónú hàn wí pé kí Aláàfin dẹ́kun rírán àwọn ọmọ àti ọkọ wọn lọ sí ojú ogun Olórí obìnrin sọ̀rọ̀ ó ní; Láyé Abíọ́dún a rójú ṣiṣẹ́ Láyé Aólẹ̀ la dàdìkalẹ̀ Láyé Arógananá lọ̀pọ̀lọ́ gbòde Abíọ́dún lọ tán ayé kọ ayé ó rójú mọ́ Gbogbo ọmọ tá a bí ló ti bógun lọ! ọ̀pọ̀ ìyàwó àṣẹ̀ṣẹ̀gbé lọkọ rẹ̀ ń jà fitafita lójú ogun wọn kò sì lóyún sínú wọn kò sì gbépọ̀n sẹ́yìn! Ẹ tètè parí ọ̀tẹ̀ yìí; Kóníkòyí ó le rogun ọba aa oi Èyí wà lára ìdí tí Ọ̀yọ́ kò fi lè ran Òwu lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àdéhùn tí wọn dìjọ ṣe wí pé tí ọwọ́ Òwu kò bá ká ogun tí Òwu ń jà láti paná òwò ẹrú àwọn a fọmọ ogun ránṣẹ́ Ní pàtàkì ọ̀rọ̀ bí ètò òṣèlú IléIfẹ̀ kò ṣe ní bàjẹ́ tí ti Ìjẹ̀bú náà kò ṣe ni di rádaràda àti èròńgbà bí Òwu tó jẹ́ igi ìdènà fún ètò ìṣèlú àti ètò ọrọ̀ajé wọn yóò ṣe di mímú kúrò lọ́nà jẹ wọn lógún Tí a bá tún wo ètò òṣèlú abẹ́lé ìlú kọ̀ọ̀kan a ó rí i pé ọba kọ̀ọ̀kan kò dá ìlú ṣe Awùjalẹ̀ fọ̀rọ̀ ìlú lọ àwọn ìjòyè rẹ̀; ó jẹ́ kí wọn sọ sí ọ̀rọ̀ ogun tí wọn fẹ́ fi ja Òwu Bákan náà Ọọ̀ni fi ọ̀rọ̀ lọ Balógun àti Abọrẹ̀ tí Olówu náà sì fọ̀rọ̀ lọ Akọgun Nígbà tí a rí Aláàfin lórí àlééfà òun pẹ̀lú àwọn Ọ̀yọ́mèsì ni a rí tí wọn ń wá ìdáhùn sí oríṣìíríṣìí ìṣòro tí ó dojú kọ ìlú ÈTÒ ÀÀBÒ Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa ogun ó yẹ kí a lè mẹ́nuba ètò ààbò ìlú Ó hàn nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ wí pé ìlú olódi ni ìlú Òwu yìngbìn Ó sòro fún ogun láti ya lu ìlú wọn Kó dà bí wọ́n ṣe dáko sẹ́yìn odi ni wọn dáko sínú odi Ìgbà tí wọ́n jẹ oúnjẹ inú odi wọn tán tí ìyàn sì mú wọn ni ọwọ́ àwọn ọ̀tá tó tẹ̀ wọn Yàtọ̀ sí èyí lílo odi bí ààbò lílo ohun ìjà lọ́pọ̀ lílo oògùn ọgbọ́n inú náà wà lára ohun tí a fi ń dáàbò bo ìlú ẹni Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ọgbọ́n inú ni olúwòó lò láti dáàbò bo Ìwó lọ́wọ́ Òwu Ó gba àwọn Ifẹ̀ láàyè láti kó ọmọ ogun jọ sí Adúnbíẹyẹ tí ó jẹ́ ilé Ìwó Ó jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún olówu wí pé òun kò fún wọn láàyè Ọgbọ́n tí ó ń dá ni wí pé tí Ifẹ̀ bá lè borí Òwu kò ní séwu fún Ìwó nípa Òwu Ọ̀nà ìsààbò kan ni èyí Olúwòó dáhùn ó ní; Sọ fún olówu pé nítọ̀ọ́ọ́tọ́ ni Ìfẹ́ ń fẹ́ kí Ìwó ran òun lọ́wọ́ ṣùgbọ́n mo kọ̀ jálẹ̀ pẹ̀lú wọn Ní ti orí ilẹ̀ Ìwó tí wọn gbà fi dìgbòlu Òwu wọn kò sọ fún mi tẹ́lẹ̀ o Sàdédé ni ìròyìn náà kàn mí ku bí eégún ó ru pé Ifẹ̀ atòwu ń jà níbi tódò Ọ̀ṣun àtọ̀bà ti sàn pàdé Sọ pé mo ti gbọ́ ohun tólówu sọ o oi Ẹ̀SÌN YORÙBÁ Ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn jẹ Yorùbá lógún Kò sí ohun tí Yorùbá ṣe tí ẹ̀sìn wọn kò ní nípa pàtàkì nínú rẹ̀ Kí àwọn Ìjẹ̀bú tó kógun lọ bá Òwu wọ́n bọ òrìṣà Ògègètielè oi Ifẹ̀ bọ Oòduà Ọ̀rànmíyàn àti gbogbo ọ̀kànlénírínwó irúnmọlẹ̀ tí ń bẹ lóòtù Ifẹ̀ Bákan náà ni Òwu rúbọ sí àwọn àgbààgbà márùnún tó wọlẹ̀ nílẹ̀ Òwu A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Àyàkokońnàkí sọ pé; Ìwọ Oòduà máa gbọ́ọ Ìwọ Ògún lákaayé máa gbọ́ o Ìwọ Ọbalùfọ̀n máa gbọ́ o Ẹ̀yin àgbà márààrún tó wọlẹ̀ nílẹ̀ Òwu; Ògbògbóńdu Àmọ̀tàkò tó wọlẹ̀ nílẹ̀ Òwu Olókose tó wọlẹ̀ tó detu inú igbó Ẹẹ́kọọ́sìn Gbọ̀ńkáà tó wọlẹ̀ nígbàlẹ̀ Tó dàgbọ̀nrín abìwo ṣanṣan Amúnimì Baralọ́rọ̀ tó dẹ̀ṣẹ tó dẹyọ́lọ́ tó ń yọ́ kiri oi Bí ẹ̀sìn ṣe jẹ ara ìgbàgbọ́ wọn náà ni a ó lè yọ ìgbàgbọ́ nínú oògùn sílẹ̀ pẹ́kípẹ́kí ni wọ́n dìjọ ń rìn Nínú eréonítàn yìí a rí idán tí Yorùbá lè fi oògùn pa lójú ogun Ní ojú ìwé kọkànlá a rí bí Akọgun Òwu ṣe fọwọ́ ra àyà rẹ̀ tí ó sì fa ọfà Balógun Ifẹ̀ tí ó ti wọl sí i láyà yọ Bákan náà ni a rí i tí ó bẹ̀rẹ̀ sí rẹ Balógun Ìjẹ̀bú tapá tẹsẹ̀ nígbà tí ó gbé Akéréburú tí Akéréburú tẹnu bọ ọfọ̀ ó ní; Àgbéró nikún ń gbọwọ! Àgbéro ni sìgìdì í gbédà Àgbéro ni tọwọ́ ẹ oi Bí Akéréburú ṣe ń pọfọ̀ náà ni a rí i tí Awùjalẹ̀ ń ṣẹ́ èpè tí ó sì tún ń tàsẹ Gbogbo wọn ni wọ́n rántí pé ẹjọ́ là á ba oògùn rò kí a tó sà á Àmọ́ sá bí wọn ṣe káràmásìkí ẹ̀sìn tó nínú eré yìí tí wọn fọ̀rọ̀ lọ gbogbo àwọn òrìṣà tó wọ́n kò fọ̀rọ̀ wọn lọ ifá Wọn kò sì bèèrè fún ìtọ́ni A lérò wí pé èyí ló fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣìṣe tí àwọn ìlú tó ń jara wọn lógun ṣe tí ó fi di pé àwọn ọmọ bàbá kan náà gbógun ti ara wọn Ṣùgbọ́n sá eléyìí lè jẹ́ àmọ̀ọ́nmọṣe bóyá òńkọ̀wé kò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ifá bọ ọ̀rọ̀ àwọn tí wọn ń bara wọn jà kí àṣìṣe lè wáyé kí ìtàn inú eré náà lè lọ bí ó ṣe fẹ́ kí ó lè ráyè ránṣẹ́ tí ó mú un lọ́kàn sí àwùjọ wa ÌPÈ FÚN ÌPADÀ ÌṢỌ̀KAN Èyí ni ibi tí Ẹ̀yìnlàárò ti kó àwọn aṣojú ẹ̀yà Yorùbá tí wọn ń gbógun tira wọn jọ Àwọn aṣojú náà ni wọ̀nyí; Ọlọ́gbọ́nilẹ̀ Ọ̀yọ́ Ọ̀mọ̀ràn Ifẹ̀ Májẹ̀ẹ́kódùnmíòdeẸ̀gbá Láké Àyàkokońnàkí ọmọ Egbèjì Òwu Olówólayémọ̀ ọmọ Awùjalẹ̀ àti Adégbáremú ọmọ Èwinílẹ̀Adó Ẹ̀yìnlàárò tí ó ti fi yé wọn pé òun ni bàbá wọn àgbà bèèrè ìdí tí wọ́n fi ń dira ogun láìsí ogun Wọn sì dáhùn pé torí ìdágìrì tó lè fẹ́ da ọkùnrin lọ́nà ni Bákan náà ni wọ́n panu pọ̀ pé kì í ṣe ìdágìrì tó lè dé láti òde bí kò ṣe láti ọwọ́ ara ilé nítorí pé ilé ni ọ̀tá wà Èyí tọ́ka sí i pé àwọn ọmọ Oòduà ni wọ́n ń digun sí ara wọn nígbà tí ogun jíjà tilẹ̀ dàbí ẹni pé ó ti parí Aṣojú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bẹ̀rẹ̀ sí wí àwíjàre Wọ́n ń fẹ̀sùn kan ara wọn ní ọ̀kanòjọ̀kan Nígbà náà ni Ẹ̀yìnlàárò wá lahùn tí ó sì wí pé; Èmi ni mo wo ẹ̀yìn wà tí mo sì rí i bílẹ̀ Oòduà ti bàjẹ́ tó tí mo rí i pé wọn ti fohun sọlé ọlá dahoro; tí mo sì rántí ọ̀rọ̀ àwọn babańlá wa pé àgbà kì í wà lọ́jà kórí ọmọ tuntun wọ́ ni mo ṣe pe ọlọ́gbọ́n ilẹ̀ Ọ̀yọ́ pé àwọn tó pètepèrò tí wọ́n wólé ọlá; kí wọn ó pe ara wọn jọ kí wọn ó túnlé ọlá mọ oi ÌLÒÈDÈ NÍNÚ ÌWÉ ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀ Èdè ni ohun èlò pàtàkì tí òńkọ̀wé fi ń ṣe ọnà nínú iṣẹ́ aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ wọn Wọ́n máa ń sa ọ̀rọ̀ lò wọn máa ń yán ọ̀rọ̀ lò láti fi ṣe ẹwà sí ara iṣẹ́ àtinúdá wọn Àkànlò ni èdè tí òńkọ̀wé máa ń lò tí iṣẹ́ aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ wọn ṣe máa ń wu ènìyàn lórí tí wọn máa ń fi èdè tí ó wuyì gbé òye àti ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ wọn yọ Onírúurú bí aṣọ alágẹmọ ni àwọn ọnà èdè tí òńkọ̀wé máa ń fi ṣe ẹwà sí ara iṣẹ́ wọn Díẹ̀ lára irú ọnà èdè bẹ́ẹ̀ ni; àfiwé àwítúnwí àjùmọ̀rìn ọ̀rọ̀ ìfọ̀rọ̀dárà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ÀFIWÉ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ohun tí ó bá jọ ohun ni a máa ń fi wé ohun èpo ẹ̀pà jọ pósí ẹ̀líírí A máa ń ṣe àmúlò àfiwé nínú lítíréṣọ̀ kí ohun tí a ń sọ ba à lè yé ènìyàn ṣùgbọ́n ìlòèdè fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú iṣẹ́ aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ púpọ̀ Nígbà mìíràn a lè fi ohun tí a mọ̀ dunjú ní àwùjọ wé ohun tí a kò mọ̀ Bákan náà ni a lè fi ohun méjì tí a mọ̀ ní àwùjọ wé ara wọn A lè fi ohun tí ó ga wé ara wọn tàbí tí ó tóbi bákan náà rí bákan náà wé ara wọn Èròńgbà lílo àfiwé ni láti mú kí a ní òye nípa ohun tí a fi ń wé ara wọn kí ó sì lè yé àwa tí a ń kà á A lè pín àfiwé sí ìsọ̀rí méjì kí ó ba à lè rọ̀ wá lọ́rùn láti lè ṣe àlàyé; i Àfiwé tààrà ii Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ ÀFIWÉ TÀÀRÀ Èyí máa ń ní àwọn kókó méjì tí wọn dúró ní igun kọ̀ọ̀kan àwọn kókó méjì yìí gbọdọ̀ ní oríta tí wọn ti pàdé Èyí ni ohun ganan tí ó pa wọn pọ̀ Àwọn ohun méjì yìí lè kọ ojú sí ara wọn tàbí kí wọn kọ ẹ̀yìn sí ara wọn Bákan náà àwọn ọ̀rọ̀ atọ́ka inú àfiwé tààrà ni bí i ÀFIWÉ ẸLẸ́LỌ̀Ọ́ Èyí yàtọ̀ sí àfiwé tààrà nítorí pé ó máa ń ṣe àgémọ́nu àwọn okùn ọ̀rọ̀ bí Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ohun méjì tí a fi ń wé ara wọn yìí kì í lọ tààrà Ohun tí ó pa wọn pọ̀ máa ń ní ìtumọ̀ ẹ̀dá Àpẹẹrẹ àfiwé tààrà tí a rí nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ nìyí nígbà tí Oníkòyí ń sọ̀rọ̀ ó ní; Ọba ní bí Olówu bá kọ̀ láti dá wọn lẹ́kun Ṣàngó Aláàfin yóò kùn bí orò wà bá wọn níbẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò máa sọ ẹdun lu igi ọ̀pẹ níbẹ̀; kí ó má wà á jẹ́ pé ẹdun ààrà máa le sán lu Òwu pẹ̀lú oi Nínú àpẹẹrẹ yìí a rí pé orò ló máa ń kù orò sì jẹ́ òrìṣà kan tí ó lágbára Èyí ni òńkọ̀wé ṣe fi Ṣàngó Aláàfin wé orò pé tí wọn ba wá bá níbẹ̀ wàhálà a ṣẹlẹ̀ Àfiwé náà ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Oníkòyí ń sọ Àpẹẹrẹ mìíràn tún ni èyí tí òńkọ̀wé fi sẹ́nu agbẹnusọ ìlú ó ní; Kábíyèsí gbogbo a kí yín Ẹ kú báyé ti dà yìí o! Àwa laṣojú gbogbo ìlú pata Wọ́n ní ká sọ fún yín pé kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní pé ká máa sọ fún yin mọ́ kí ẹ tó mọ̀ pé ayé kò gún mọ́ òde ìlú kò tòrò Ayé le koko bí ojú ẹja wọn ní kí ẹ bá wa tún ayé ṣe o Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kọjá àfaradà oi Tí a bá wo àpẹẹrẹ òkè yìí ojú ẹja jẹ́ ohun tí ó le Èyí ni òńkọ̀wé ṣe fi bí ayé ṣe le wé ojú ẹja Agbẹnusọ ìlú ni òńkọ̀wé fi ọ̀rọ̀ yìí sí ní ẹnu láti lè fi bí ìlú ṣe le tó han òńkàwé Òńkọ̀wé rí èyí lò nítorí pé ohun tó le koko ló fi ayé wé Ìlò èdè òńkọ̀wé nínú àpẹẹrẹ yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ohun tí ó ń ṣàlàyé ÌFỌ̀RỌ̀DÁRÀ Èyí ni fífẹ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ lójú Ète lílọ́ èdè lọ́rùn nípa fífi kókó ọ̀rọ̀ dárà ni ó bí ìfọ̀rọ̀dárà Nínú ọnà èdè yìí a máa ń ya lára odidi ọ̀rọ̀ kan tí a ó ṣe àwítúnwí rẹ̀ ní ọ̀nà tí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò fi máa yípadà tí ìtumọ̀ rẹ̀ yóò sì máa bá a yípadà Àpẹẹrẹ tí a rí mú jáde nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ni ti ọ̀mọ̀ràn tó sọ pé; Wọ́n ní kikan ló kan ni wọ́n ń pè lọ́bàkan; ọbàkan ni wà nítòótọ́ Ká má jẹ́ kí tiwa ó kan ríro lo;ó ro ni wọ́n ń pè lórogún; ka má jẹ́ kí tiwa ó ro o Ẹ jẹ́ ká fara wa mọ́ra ni ká sì máa pe ara wa ní Arákùnrin mi látòní lọ oi Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí òńkọ̀wé fi àwọn ọ̀rọ̀ bí kan àti ro dárà láti gbé kókó tí ó tẹnumọ́ jáde kí ni òńkọ̀wé fi kún kan tí ó sì di kíkan nígbà tí ó fi ri tí ìyẹn náà sì di ríro òńkọ̀wé lo ọnà èdè yìí láti gbà òun tí ó jẹ ẹ́ lọ́kàn jáde Ọ̀nà tí ó sì gbà lo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ohun tí ó ń sọ Kò sì tàsé ara wọn Tí a bá tún wo kókó ọ̀rọ̀ yìí a rí wí pé òńkọ̀wé fi ọ̀rọ̀ tí ó lò láti fi dárà sí ẹnu ẹ̀dá ìtàn ti ó jẹ́ ọ̀mọ̀ràn láti lè gba àwọn Yorùbá ti fi ogun ja ara wọn níyànjú àti láti lè jẹ́ kí ìṣọ̀kan jọba láàárín àwọn Yorùbá ÀJÙMỌ̀RÌN Ọ̀RỌ̀ Nínú ọnà èdè yìí a máa ń ṣe àmúlò ọ̀rọ̀ èrò tàbí gbólóhùn méjì tí wọn kì í ya ara wọn Tí a bá ti gbọ́ ọ̀kan ni a ó máa retí èkejì A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Abọrẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ó ní; Èyí Ọọ̀ni wí lo gbọ́ rè é ni o Ọsìnmọlẹ̀ Gbogbo èyí tó wí kárọ̀ ó rọ̀ mọ́ ọn ọmọ ọwọ́ kì í tojú ọwọ́ kú ọmọ ẹsẹ̀ kì í tojú ẹsẹ̀ ẹ́ rọ̀run oi Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí òńkọ̀wé lo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ara tí kì í ya ara wọn Àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọn lè bá ara wọn rìn nínú gbólóhùn Fún ìdí èyí ọ̀nà tí òńkọ̀wé gbà lo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ara wọn ó sì bá ìṣẹ̀lẹ̀ tó lò ó pẹ̀lú mu ÀWÍTÚNWÍ Àwítúnwí yìí lè jẹ́ ti ẹyọ ọ̀rọ̀ awẹ́ gbólóhùn odidi ìlà tàbí ti èrò ÀWÍTÚNWÍ ẸYỌ Ọ̀RỌ̀ A lè ṣe àmúlò ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo nígbà méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní orí ìlà kan náà ní orí ìlà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ A rí àpẹẹrẹ rẹ̀ nígbà tí Àyàkokońnàkí ń sọ̀rọ̀ ó ní; Sọ fAláàfin yóò sì gbélé gbọ́ Ní gbogbo agbègbè yìí ta ni yóò kokà Olówu kéré kò sólúwa rẹ̀ ikú kì í sẹgbẹ́ àrùn Ṣàngó kì í sẹgbẹ́ oníbọn Akọgun Òwu ló jókòó yìí ọkùnrin làdá oi Nínú àpẹẹrẹ yìí sẹgbẹ́ ni ẹyọ ọ̀rọ̀ tí a ṣe àwítúnwí rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí òńkọ̀wé ń sọ ni pé Aláàfin ju gbogbo àwọn ọba tókù lọ fún ìdí èyí ìlò èdè yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ó sì ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ẹ̀dá ìtàn tí òńkọ̀wé fi sí lẹ́nu Àpẹẹrẹ mìíràn èyí tí a rí nígbà tí Balógun Ìjẹ̀bú ń sọ̀rọ̀ ó ní; Láì níbọn láì lọ́fà mọ! Láì lóúnjẹ! Láì lólùgbèjà! Síbẹ̀ Olówu kò tùùbá! oi Nínú àpẹẹrẹ yìí ẹyọ ọ̀rọ̀ láì ni a ṣe àwítúnwí rẹ̀ òńkọ̀wé sì lò ó láti fi ṣe ìtẹnumọ́ fún kókó tí ó fẹ́ rán s àwùjọ ni Ẹ̀dá ìtàn tí ó jẹ́ olórí ogun àwọn Ìjẹ̀bú ni òńkọ̀wé fi èdè yìí sí lẹ́nu nítorí náà ìlò èdè yìí àti ẹ̀dá ìtàn náà ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ara wọn ÀWÍTÚNWÍ ODIDI ÌLÀ TÀBÍ GBÓLÓHÙN Èyí ni ṣíṣe àwítúnwí odidi ìlà kan tàbí odidi gbólóhùn kan tẹ̀lé ara wọn A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Akéréburú ń sọ̀rọ̀ ó dáhùn ó ní; Oníbẹ̀ńbẹ́ fìlù sí i! Itańta rùkù ta rùkù Itańta rùkù ta rùkù Ẹ máa lè wọn lọ ń só Ẹ máa lè wọn lọ ń só !!! oi Nínú àpẹẹrẹ yìí a rí i dájú pé odidi ìlà ni òńkọ̀wé ṣe àwítúnwí rẹ̀ òńkọ̀wé fi ọ̀rọ̀ yìí ya àwòrán bí ogun Òwu ṣe ń lé ogun ọ̀tá lọ hàn wá ni Ọ̀kan lára àwọn akópa nínú ogun náà ni òńkọ̀wé fi ọ̀rọ̀ náà sí lẹ́nu èyí mú kí ọ̀rọ̀ náà ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ÀWÍTÚNWÍ AWẸ́ GBÓLÓHÙN Irúfẹ́ àwítúnwí yìí kì í mú odidi gbólóhùn tán abala kan lára gbólóhùn ló máa ń mú Abala kan yìí náà ni a sì máa ń ṣe àwítúnwí rẹ̀ A rí àpẹẹrẹ èyí nígbà tí Ọlọ́gbọ́n ń sọ̀rọ̀ ó ní; Ẹ̀yin arákùnrin mi! Oníkálùkù ó dọwọ́ọ̀ rẹ! Ọ̀mọ̀rànIfẹ̀ ó dọwọ́ọ̀ rẹ Ọlọ́gbọ́nỌ̀yọ́ ó dọwọ́ọ̀ rẹ; Ọmọ Awùjalẹ̀ ó dọwọ́ọ̀ rẹ; Ọmọ Egbáláké ó dọwọ́ọ̀ rẹ; Ẹ wí fúnra yín ó dọwọ́ọ̀ àwa o! Baba ti sọ̀rọ̀ ẹ jẹ́ ká gbọ́ oi Nínú àpẹẹrẹ yìí a rí i pé apá kan lára gbólóhùn ni òńkọ̀wé ṣe àwítúnwí rẹ̀ tí ó sì jẹ́ pé ó ní kókó tí òńkọ̀wé fẹ́ kí àwọn òńkàwé rẹ̀ mọ̀ Fún ìdí èyí èdè tí òńkọ̀wé fi sí ẹ̀dá ìtàn yìí lẹ́nu ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tí òńkọ̀wé lò ó fún ÒWE Òwe ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi àrògún àti àròjinlẹ̀ gbé kalẹ̀ láti fa ọgbọ́n yọ àti láti fún ni ní ìtumọ̀ pàtàkì A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Akọgun Òwu ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Olúwòó ó ní; Olówu wá sọ pé ó rí bẹ́ẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ o ohun tí òun fẹ́ kí Olúwòó mọ̀ ni pé; bí a ti ń yọ̀ só là ń yọ́ gbọ́ Ina tá a dá nílé gọ̀gọ̀ rẹ̀ ń yọ lóde Másòó lòògùn má gbọ́ o Olówu ni gbogbo ìwà tOlúwòó hù lórí ọ̀rọ̀ yìí lòun mọ̀ pátápátá oi Nínú ọ̀rọ̀ tí Akọgun sọ a rí wí pé òwe tí ó lò jẹ́ òwe tí ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ Òńkọ̀wé fi òwe yìí sí ẹnu rẹ̀ ní ọ̀nà tí ó bá a mu kò lo òwe tí kò lọ pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà Àpẹẹrẹ òwe mìíràn tún ni èyí tí a rí nígbà tí ọlọ́gbọ́n ń sọ̀rọ̀ ó ní; Ìlẹ̀kẹ̀ ja sínú má ja síta; ìlẹ̀kẹ̀ já síta má já sínú ibìkan sá nìlẹ̀kẹ̀ yóò já sí? Wọn nílé ayé kò ṣe é gbé ọ̀run kò sì ṣe é lọoi Nínú àpẹẹrẹ yìí òńkọ̀wé lo òwe yìí láti lè ya àwòrán ohun tí ó ń sọ sí wa lọ́kàn àti láti lè jẹ́ kí kókó tí ó rán sí àwùjọ di mímọ̀ fún ìran Yorùbá Èdè tí ó fi sí ẹnu ẹ̀dá ìtàn yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ nínú eré náà ÀKÀNLÒ ÈDÈ Àkànlò èdè ni lílo èdè lọ́nà tí ó yàtọ̀ sí bí a ti ṣe lè lò ó nínú èdè ojoojúmọ́ Ìtumọ̀ tí a máa ń bá nínú àkànlò èdè yóò yàtọ̀ sí ohun tí a bá nínú ìhun òkè A tún lè sọ pé àkànlò èdè ni ọ̀rọ̀ tàbí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí Yorùbá ń lò láti fi sọ̀rọ̀ tí wọn kò bá fẹ́ sojú abẹ níkòó A rí àpẹẹrẹ èyí nígbà tí Olówólayémọ̀ ń sọ̀rọ̀ ó ní; Bèèrè dáadáa o Abọrẹ̀! Nítorí pé Òwu kì í ṣẹran rírọ̀ rárá o ẹran líle ni wọn Bèèrè dáadáa o oi Nínú àpẹẹrẹ yìí òńkọ̀wé lo ọ̀rọ̀ yìí nítorí kò fẹ́ sọ ojú abẹ níkòó dípò kí òńkọ̀wé sọ pé Òwu burú ó lo ẹran líle Fún ìdí èyí èdè yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn náà ỌFỌ̀ Ìgbàgbọ́ Yorùbá nínú agbára ọ̀rọ̀ ẹnu ló bí ọfọ̀ Ọfọ̀ ni ewì àwíṣẹ tí a máa ń lò láti pàṣẹ fún ènìyàn tàbí láti mú kí ènìyàn ṣe ìfẹ́ inú ẹni A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Balógun Ẹgbá ń pọfọ̀ fún ogun tó fẹ́ lọ jà ó ní Ń ó lọ ń ó bọ̀ Ń ó dé e dandan Nítorí pé dídédídé ni tewé adé Bíbọ̀ bíbọ̀ ni tẹ̀bọ̀yè Ẹni bá pé ń má dé é BỌlọ́run fẹ́ ń kò ní í bọ̀ bá aoi Nínú àpẹẹrẹ yìí a rí pé òńkọ̀wé lo èdè tó wuyì láti fi gbé ọfọ̀ yìí kalẹ̀ ó sì ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tí òńkọ̀wé lò ó fún nínú eré náà Bákan náà tún ni pé gbogbo ọfọ̀ tó jẹyọ nínú eré náà ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ibùdó ìtàn ORIN Aṣàfihàn àwùjọ ni orin jẹ́ a kì í dédé kọrin ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ibi tí ènìyàn bá wà ni yóò sọ irú orin tí ènìyàn lè kọ A rí àpẹẹrẹ orin nígbà tí Akọgun Òwu ń kọrin ní ojú ogun ó ní; Akínjọbí ọmọ Ajíbọ̀sìn Lẹ́ẹ̀kan yìí kọ Ka wá á pelé sìnrìn ni ó borí Òwu Lẹ́ẹ̀kan yìí kọ oi Nínú àpẹẹrẹ yìí orin yìí jẹyọ nígbà tí àwọn Òwu fẹ́ gbé ogun lọ sí Ifẹ̀ tí wọn ní láti kọ́kọ́ bọ òrìṣà wọn Orin yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ibùdó ìtàn àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà Àpẹẹrẹ orin mìíràn ni èyí tí àwọn Òwu kọ lójú ogun wọ́n ní; Ase kò le jà Tító ló tóbi bàńku Ìjẹ̀bú kòlejà! Tító ló tóbi bàńku oi Nínú àpẹẹrẹ yìí orin yìí jẹyọ nígbà tí àwọn Òwu àti Ìjẹ̀bú ń jà lójú ogun ó sì ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ibùdó ìtàn nítorí pé òńkọ̀wé kò lo orin gbẹ̀fẹ́ orin ọ̀tẹ̀ tí a máa ń bá pàdé ni ó lò Fún ìdí èyí orin yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ inú eré náà ÀRÍWÍSÍ Tí a bá wo gbogbo èdè tí òńkọ̀wé lò nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ a rí i pé ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ara wọn Ìṣewẹ́kú ni ìbáramu àwọn èròjà inú iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ kan fún ìdí èyí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé náà ṣe wẹ́kú pẹ̀lú àwọn ibùdó ìtàn Bẹ́ẹ̀ náà tún ni èdè ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ìtàn bẹ́ẹ̀ sì ni ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe wẹ́kú pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ìtàn Èdè tí òńkọ̀wé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ lò bá ìtàn rẹ̀ mu ó sì lò wọ́n dáadáa bí ó ṣe yẹ kí ó lò ó Bákan náà tún ni pé ìlò èdè òńkọ̀wé jẹ́ àwọn èdè tí ó lọ́ọ̀rìn tí ó sì ní ìṣewẹ́kú pẹ̀lú àwọn ìwà tàbí ìhùwàsí àwọn ẹ̀dá ìtàn tí òńkọ̀wé fi sí wọn lẹ́nu Bí àpẹẹrẹ àwọn èdè tí ó fi sí àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ lẹ́nu bí i ọba Aólẹ̀ tí ń ṣe ọba Ọ̀yọ́ Aláàfin a rí i pé èdè adarí ni Àwọn èdè ẹnu rẹ̀ tún jẹ́ èdè tí ó fihàn pé ọba ní í ṣe Àwọn èdè àṣẹ bí àpẹẹrẹ nígbà tí Aláàfin rán Oníkòyí lọ sí ọ̀dọ̀ Àyàkokońnàkí lórí ohun tí ó fẹ́ kí ó ṣe lórí òwò ẹrú títà lọ́jà Apòmù Ó ní; Ọba ní kí o dìde kíá kí o wa egbò dámọlẹ́kun fún wọn níbẹ̀ kí òun sì gbélé gbọ́ lọ́yọ̀ọ́ pé eégún wọn ti wọlẹ́ sin níbẹ̀ àbàlà wọn sì ti wọlẹ̀ sin oi Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí a rí i pé ó pàṣẹ ni kì í ṣe pé ó ń bẹ̀bẹ̀ Fún ìdí èyí èdè tí òńkọ̀wé lò yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń lọ Bákan náà tí a bá tún wo ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn aṣáájú ogun kọ̀ọ̀kan bí i Akọgun Òwu Balógun Ifẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ a rí pé èdè akin ni òńkọ̀wé fi sí wọn lẹ́nu bí àpẹẹrẹ nígbà tí Balógun Ifẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ó ní; Ẹ̀yin ara Òwu sáwa le tọ̀ wá tẹ̀yin tàdá lásán lọ́wọ́ yín? Àwa tàa níbọn àtẹ̀tù rẹ́kẹrẹ̀kẹ! Tàbọn tàbọn yín orí odi tẹ ẹ gbójúlé ikú ti pá Pàtàkì tí ẹ fẹ̀mí tẹ̀ wọn ti tọwọ́ ìbọn wa ṣòfò dànù Ẹ̀yin ẹ̀tahóró tó kù sílẹ̀ ẹ mú àdá lọ́wọ́ ẹ ń tọ̀ wà bọ̀ Ẹ fi kú siré oi Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí a rí i pé èdè tí òńkọ̀wé fi sí ẹnu ẹ̀dá ìtàn yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń lọ nínú ìtàn náà Bákan náà tí a bá wo èdè tí òńkọ̀wé fi sí Abọrẹ̀ lẹ́nu a rí i pé ó jẹ́ èdè tí àwọn ènìyàn máa ń bọ̀wọ̀ fún nítorí pé wọn jẹ agbẹnusọ àwọn òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá àti wí pé wọn lè rán ẹnikẹ́ni níṣẹ́ nítorí pé bí òrìṣà bá ṣe rán wọn ni wọn máa ń jẹ́ ẹ A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Abọrẹ̀ Ìjẹ̀bú àti Awùjalẹ̀ ń bọ òrìṣà ọba ńlá Abọrẹ̀ ní pé; Ọ̀rọ̀ kan náà tí obì ti sọ náà ló tún sọ Kábíyèsí a ti rúbọ tán ẹbọ ti fín ẹbọ ti da Iṣẹ́ tẹ́ ẹ bá fẹ́ rán àwọn irúnmọlẹ̀ ẹ rán wọn báyìí oi Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí a rí i pé èdè tí òńkọ̀wé fi sí ẹnu ẹ̀dá ìtàn yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà Bákan náà tún ni tí a bá wo èdè tí òńkọ̀wé fi sí ẹnu àwọn ọlọ́jà a rí i pé èdè tí ó kún fún àpọ́npo ni wọ́n máa ń lò èdè tí ó sì máa ń fani mọ́ra ni pẹ̀lú bí àpẹẹrẹ a rí ìpolówó ọjà nínú ọjà Apòmù tí obìnrin Ìjẹ̀bú kan ti polówó ataare tí ó ń tà ó ní; Ẹ bá mi rà á o Pọ̀ọ́ńtọ̀ọ̀ọ̀ Ọ̀pọ̀kúyọ̀kú lataaree mi o o Olóko ò gbowóóó! oi Tí a bá wo àpẹẹrẹ yìí a rí i pé ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ Bákan náà tún ni pé ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ibùdó ìṣẹ̀lẹ̀ Bákan náà tí a bá tún wo èdè ẹnu àwọn olóyè tàbí ìjòyè a rí i wí pé ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tí òńkọ̀wé lò fún un nítorí pé àti ọba àti ìjòyè ni wọ́n jọ máa ń yanjú gbogbo dàrúdàpọ̀ tí ó bá dé bá ìlú A rí àpẹẹrẹ èyí nígbà tí àwọn Ọ̀yọ́mèsì àti Aláàfin ń jíròrò lórí rúdurùdu tó dé bá ìlú wọn Baṣọ̀run Kábíyèsí ìlú Ọ̀yọ́ ń kùn wọn sì ń sọ̀rọ̀ Ìlú Ọ̀yọ́ wú ó fẹ́ bẹ́ ilẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ka bi kábíyèsí pé òtútù ń mára ayé ará ọ̀run kò sì faṣọ bora! Ọlọ́gbọ́n wọ́n ní kọ́ba ó tètè wa nńkan ṣe sí i Àrokò ọ̀rọ̀ ni wọ́n pa fún wa àbí? Èsì wo ni ká fọ̀ fún wọn Àgbàakin Kábíyèsí! Àrokò ọ̀rọ̀ kọ́ òwe ni Gbogbo wa láti mọ ohun tí wọn ń wí Èsì wo ni ká fọ̀ ránṣẹ́ sí wọn?oi Nínú àpẹẹrẹ yìí èdè tí òńkọ̀wé fi sí àwọn ẹ̀dá ìtàn yìí lẹ́nu ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń lọ lọ́wọ́ nínú ìtàn náà Bákan náà tí a bá tún wo ibùdó ìtàn nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ a rí i wí pé ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ inú eré náà bí àpẹẹrẹ níbi tí wọn tí ń polówó ọjà a rí pé àárín ọjà ni èyí ti máa ń wáyé Bákan náà ibùdó ìtàn ojú ogun a tún rí pé ojú ogun ni àti máa ń rí oríṣiríṣi orin ọ̀tẹ̀ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ọmọ ènìyàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ fún ìdí èyí ibùdó ìtàn náà ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ inú eré náà Lẹ́yìn tí a ti yẹ èdè òńkọ̀wé wò fínífínní a rí pé ó ní èdè kan tí òńkọ̀wé fẹ́ràn láti lò èyí ni èdè tí ó tayọ nínú ìwé yìí Tí a bá ń sọ̀rọ̀ lórí ìtayọ èyí ni ohun tí ó jẹ́ pé òun ni òńkọ̀wé lò jù nínú iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ rẹ̀ ìtayọ tí a ń wí yìí lè jẹ́ ríru tàbí yíyọ sókè apá kan lára ìhun ju èkejì lọ orin ni ó tayọ jù nínú gbogbo èdè tí òńkọ̀wé lò Ó lo òwe méjìlélógún nígbà tí àfiwé jẹ́ méjìlélógún bákan náà tí àwítúnwí sì jẹ́ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tí ìfọ̀rọ̀dárà sì jẹ́ méjìlá Àkànlò èdè jẹ́ méjì bẹ́ẹ̀ náà ni àjùmọ̀rìn ọ̀rọ̀ náà jẹ́ méjì ọfọ̀ sì jẹ́ mọ́kànlá nígbà tí orin tí ó tayọ sì jẹ́ mẹ́rìndínláàdọ́rin Àwòrán gíráàfù yìí yóò túbọ̀ ṣàlàyé ohun tí a ń sọ síwájú sí i ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ ÀTI ÌLÒ ÈDÈ TÍ Ó JẸYỌ Iye àwọn ìlò èdè Àwọn ìlò ede Ibi ìjẹyọ Ìgbà ìjẹyọ Ibi ìjẹyọ Ìgbà ìjẹyọ Ibi ìjẹyọ Ìgbà ìjẹyọ Ibi ìjẹyọ Ìgbà ìjẹyọ Ibi ìjẹyọ lápapọ̀ Ìgbà ìjẹyọ lápapọ̀ Àkànlò èdè Àjùmọ̀rìn ọ̀rọ̀ Ọfọ̀ Ìfọ̀rọ̀dárà Àfiwé Òwe Àwítúnwí Orin ORÍ KẸ́RIN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ ÌFÁÀRÀ Yorùbá bọ̀ wọ́n ni kò sí ohun tó ní ìbẹ̀rẹ̀ tí kì í lópin bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni iṣẹ́ àkànṣe yìí jẹ́ nítorí a ti mẹ́nu ba onírúurú ìlò èdè pàápàá jùlọ nínú ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Bákan náà a tún sọ̀rọ̀ lórí ohun tí ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè jẹ́ Síwájú sí i a ṣe àyẹ̀wò lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè jùlọ nínú eréonítàn Yorùbá Ní ìparí a sọ̀rọ̀ ní ṣókí nípa àbọ̀ ìwádìí yìí a wo àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí A kò gbàgbé láti gba àwọn olùwádìí ọjọ́ iwájú ní ìmọ̀ràn lórí ọ̀nà láti ṣe àṣeyọrí ÌSỌNÍṢÓKÍ ÀBỌ̀ ÌWÁDÌÍ Nínú iṣẹ́ àkànṣe yìí a ti sọ̀rọ̀ lórí onírúurú ọ̀nà tí a lè gbà ṣe ìwádìí lọ́kànòjọ̀kan gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú ìpilẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí a ṣe ìfáàrà lórí iṣẹ́ tí à ń gbéyẹ̀wò èrèdí iṣẹ́ ìwádìí ibi tí ìwádìí gbòòrò dé àńfààní iṣẹ́ ìwádìí àti ètò ìwádìí iṣẹ́ yìí Bákan náà a tún ṣe àgbéyẹ̀wò aáyan ọ̀mọ̀ràn èyí ni iṣẹ́ àwọn aṣáájú A wo ohun tí èdè jẹ́ ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè eréonítàn Yorùbá gẹ́gẹ́ bí àwọn asíwájú ṣe ṣàlàyé wọn Bákan náà a ṣàlàyé nípa tíọ́rì ìṣàmúlò èyí tí í ṣe tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè Síwájú sí i a ṣe ìsọníṣókí ìtàn ìgbésí òńkọ̀wé ìtàn inú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Bákan náà a tún wo àwùjọ tó bí ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ A tún ṣe àyẹ̀wò àwọn ìlò èdè nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ bí i; òwe àfiwé orin àjùmọ̀rìn ọ̀rọ̀ àkànlò èdè ìfọ̀rọ̀dárà àwítúnwí ọfọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Lákòótán a tún mẹ́nuba àwọn èdè tí òńkọ̀wé fi sí ẹ̀dá ìtàn kọ̀ọ̀kan lẹ́nu àti àwọn ibùdó ìtàn tí òńkọ̀wé lò A sì tún wo ìlò èdè tí ó tayọ jù ÀLÉÉBÙ ÀTI ÀMÚYẸ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Tí a bá ń sọ̀rọ̀ lórí àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí èyí ni àwọn nńkan tí ó kù díẹ̀ ká à tó fún iṣẹ́ àkànṣe yìí lára wọn sì ni pé àkànpọ̀ òwe àti àwítúnwí asán ti pọ̀ jù fún òńkọ̀wé yìí Síwájú sí i àwọn kókó tí a lè pè ní àmúyẹ nínú iṣẹ́ àkànṣe yìí ni pé ó jẹ́ kí olùwádìí mọ̀ nípa bí a ṣe ń ṣe àmúlò èdè lóríṣìíríṣìí ọ̀nà Bákan náà ó tún fún olùwádìí ní àńfààní láti mọ̀ nípa àwọn ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ọnà èdè wọ̀nyí nítorí olùwádìí kò mọ̀ nípa èyí tẹ́lẹ̀ Bákan náà ó jẹ́ kí olùwádìí ní ìmọ̀ lórí àwọn ohun èlò tàbí èròjà tí àwọn òńkọ̀wé máa ń lò fún iṣẹ́ wọn Lákòótán ó fún olùwádìí ní àńfààní láti mọ̀ ní kíkún lórí àṣà ilẹ̀ Yorùbá pàápàá jùlọ èdè àwọn Yorùbá ÌMỌ̀RÀN FÚN ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé a kì í pín ẹran kí a máa pín ti òróńro bí yóò ṣe ti mọ ni yóò mọ A kò ní ṣàì ní ìmọ̀ràn fún àwọn tí yóò ṣe ìwádìí yìí lọ́jọ́ iwájú Ohun kìíní tí a ó gbà wọn ní ìmọ̀ràn ni pé wọ́n gbọdọ̀ máa fi èdè àti àṣà Yorùbá yangàn nítorí pé bí onígbá bá ṣe pe igbá rẹ̀ náà ni wọn yóò bá a pè é Wọn gbọdọ̀ lè jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún àwọn ará àwùjọ pé èdè Yorùbá àti àṣà Yorùbá kì í ṣe àkómẹ́rẹ̀ rárá ṣùgbọ́n tí wọn kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn ènìyàn yóò máa fi ojú bínńtín wo èdè àti àṣà wa Ní àfikún kí ó má ba à dàbí ìgbà tí à ń bẹ oníṣègùn ṣùgbọ́n tí a kò bẹ aláàárẹ̀ tí yóò lo oògùn rẹ̀ a ní láti gba àwọn òńkọ̀wé ní ìmọ̀ràn pé gbogbo ìgbà tí àwọn olùwádìí bá wá láti ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn kí wọn máa gbìyànjú láti dá wọn lóhùn fún àṣeyọrí iṣẹ́ wọn Ní àkótán ó yẹ kí a gba àwọn olùwádìí ọjọ́ iwájú ní ìmọ̀ràn pé tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìwádìí kí wọ́n ní ìforítì àti ìfaradà Èyí ni yóò ṣe okùnfà láti lè ṣe iṣẹ́ náà dé ojú àmì ÀKÓJỌ ORÚKỌ ÌWÉ Abírí Adéyẹmí O Tíọ́rì Lítíréṣọ̀ ní Èdè Yorùbá Ìjẹ̀búÒde Sebíótimọ Adéyínká Ojúṣe Òbí Olùkọ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Ìjọba Ẹbí nínú Ṣíṣe Àmúlò Èdè Yorùbá Láwùjọ nínú Yorùbá Gbòde Ajíbóyè O Lítíréṣọ̀ Yorùbá Ìlọrin Fajenyọ A Ìlò Èdè Yorùbá Nínú Ọ̀pádọ̀tun T Àkójọpọ̀ Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá Abẹ́òkúta Fátókí F Ìmọ̀ Ìṣọwọ́lo èdè nínú Ọ̀pádọ̀tun Àkójọpọ̀ Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá Apá Kejì Ọ̀yọ́ Ọ̀yọ́ Ògúndèjì PA EréOníṣe Yorùbá nínú Àjàyí Ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá Ẹ̀dá Èdè Lítíréṣọ̀ àti Àṣà Ìjẹ̀búÒde Sebíótimọ Ògúnníran L Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Ìbàdàn ÌṢẸ́ ÀTI ÌYÀ NÍNÚ ÌWÉ BÁMIDÉLÉ ẸLẸ́WÀ SÀPỌ́N BÍ ÀPẸẸRẸ ADENIKẸ APÁ KAN IṢẸ́ ÀṢEKÁGBÁ FÚN Ẹ̀KỌ́ ÀKÀGBOYÈ NÍNÚ ÌMỌ̀ ÌPÌLẸ̀ Ẹ̀DÁ Bii Eè NÍNÚ ÈDÈ YORÙBÁ NÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ YUNIFÁSÍTÌ ÌLỌRIN ÌLỌRIN NÀÌJÍRÍÀ OṢÙ ÈBÌBÌ ỌDÚN ÌFỌWỌ́SÍ Iṣẹ́ àkànṣe yìí ni a ti kà tí a sì rí i pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè àti Èdè Nàìjíríà Yunifásítì Ìlọrin Ìlọrin ALÀGBÀ LAYỌ̀ ÒGÚNLỌLÁ ỌJỌ́ ALÁBÒÓJÚTÓ OLÙYẸ̀WÒ ÌTA ỌJỌ́ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N ỌJỌ́ OLÓRÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁ ÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ÌFISỌRÍ Mo fi iṣẹ́ ìwádìí yìí sọrí Olódùmarè ọba Elétílukára bí ajere Arìbìrabata ọba a dàgbà má pàrọ̀ oyè tí kò jẹ́ kí ń kú sí ojú ọ̀nà nínú ẹ̀kọ́ mi Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyá àti bàbá mi àti Kí Ọlọ́run bá mi fi ẹ̀mí gígùn tawọ́n lọ́rẹ kí wọn ba à lè fẹ̀yìntì jẹun ọmọ ÌDÚPẸ́ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bí ènìyàn bá dúpẹ́ oore àná yóò rí òmíràn gbà Nítorí ìdí èyí mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọba ọba láíláí tí ó ṣe àtìlẹ́yìn mi láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ mi tiit dé òpin Bákan náà ni mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí mi Nítorí Yorùbá bọ̀ wọ́n ní tí kò bá sí tàgbàdo kín ni à bá máa pè lẹ́kọ Tí kò bá sí tiwọn kò le sí èmi àti Bákan náà ni ń ó tún ní gbàgbé àwọn ẹ̀gbọ́n mi tí wọ́n dúró gẹ́gẹ́ bí ìyá àti bàbá mi; aya Bámigbóyè Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìrànlọ́wọ́ wọn lórí mi Ọlọ́run a ràn ẹ̀yin náà lọ́wọ́ Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀gá mi ẹni tí ó jẹ́ alábòojútó iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí Alàgbà Layọ̀ Ògúnlọlá fún ìfaradà wọn Ọlọ́run a farabalẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ tiyín náà Ọlọ́run a bá ẹ̀yin náà ṣe iṣẹ́ yín ní àṣepé Bákan náà ni mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ mi gbogbo Ọ̀mọ̀wé Lérè Adéyẹmí HO Adéọ̀ṣun Ọmọ́léwu Ọlátúnbọ̀sún Aya J Atóyèbí Ọlọ́run kò ní fi yín sílẹ̀ nígbà kankan Bákan náà ni ó ní gbàgbé àwọn ọ̀rẹ́ mi wọ́n kú àfaradà àti àtìlẹ́yìn mi láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí àwọn bí i; Onífádé Olúbùkọ́lá Olówólayémọ̀ Ìrètíògo Adénẹ́kàn Aya Balógun Asagidigbi Òkìkíọlá mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín Ọlọ́run kò ní fi yín sílẹ̀ Bákan náà ni ọpẹ́ mi tún lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn tí a jọ ń gbé ilé mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀gbọ́n mi fún ìfaradà àti àdúrótì wọn lórí mi Bákan náà ni mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀gbọ́n ènìyàn mi pàtàkì; Àjídé Folúwakẹ́mi Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gidigidi Ọlọ́run a bá ẹ̀yìn náà ṣe ti yín parí o gbogbo wa la máa parí láyọ̀ àti àlàáfíà ÀṢAMỌ̀ Èròǹgbà iṣẹ́ àkànṣe yìí ni láti wo ìṣẹ́ àti ìyà nínú ìwé eréoitan Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Òdú ni ìṣẹ́ àti ìyà ní àwùjọ kì í ṣe àìmọ̀ olóko Iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò túṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò nípa ìṣẹ́ àti ìyà ní àwùjọ Iṣẹ́ àkànṣe yìí a jẹ́ kí a mọ̀ nípa okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà ìhà tí àwùjọ kọ sí ìṣẹ́ àti ìyà ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà Bákan náà ni a ó tún ṣe àtúpalẹ̀ ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n pẹ̀lú àfihàn ìṣẹ́ àti ìyà a ó wo ibùdó ìtàn ẹ̀dá ìtàn ìlò èdè ọgbọ́n ìsọ̀tàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Bákan náà ni a ó wo ìhà tí òǹkọ̀wé kọ sí ìṣẹ́ àti ìyà ÀTẸ ÀKÓÓNÚ Àkọlé Ìfọwọ́sí Ìfisọrí Ìdúpẹ́ Àṣamọ̀ Àtẹ Àkóónú ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Ìfáàrà Èrèdí iṣẹ́ ìwádìí Ibi tí ìwádìí gbòòrò dé Ọgbọ́n ìwádìí Àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí yìí Ètò ìwádìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN Ìfáàrà Lítíréṣọ̀ àti àwùjọ Eréonítàn Yorùbá Okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà láwùjọ Ìhà tí àwùjọ kọ sí ìṣẹ́ àti ìyà Ọ̀nà àbáyọ sí ìṣẹ́ àti ìyà Tíọ́rì ìṣàmúlò Tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì Lítíréṣọ̀ tí ó tẹ̀lé ìlànà àti èrò ORÍ KẸ́TA ÌTÚPALẸ̀ ÌWÉ BÁMIDÉLÉ ẸLẸ́WÀ SÀPỌ́N Ìfáàrà Ìtàn ìgbésí ayé òǹkọ̀wé Àhunpọ̀ ìtàn ní ṣókí Àwùjọ tó bí ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Ibùdó ìtàn gẹ́gẹ́ bí orísun ìṣẹ́ àti ìyà Ìfìwàwẹ̀dá gẹ́gẹ́ bí àfihàn ìṣẹ́ àti ìyà ORÍ KẸ́RIN ÌTẸ̀SÍWÁJÚ ÌTÚPALẸ̀ ÌWÉ ERÉONÍTÀN BÁMIDÉLÉ ẸLẸ́WÀ SÀPỌ́N Ìfáàrà Kókó ọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí àfihàn ìṣẹ́ àti ìyà Ọgbọ́n ìṣọ̀tàn gẹ́gẹ́ bí àfihàn ìṣẹ́ àti ìyà Ọgbọ́n ìṣọ̀tàn ìsọ̀rọ̀ǹgbèsì Ọgbọ́n ìṣọ̀tàn lẹ́tà Ọgbọ́n ìṣọ̀tàn amèròọkàn Ìlòèdè gẹ́gẹ́ bí àfihàn ìṣẹ́ àti ìyà Òwe Àfiwé Ìhà tí òǹkọ̀wé kọ sí ìṣẹ́ àti ìyà nínú ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ Ìfáàrà Ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí Àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí Ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú Ìkádìí Àsomọ́ Àkójọ orúkọ ìwé ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀SẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌFÁÀRÀ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ìpàkọ́ onípàkọ́ làáárí ni lẹ́ni ní máa ń rí tẹni Èyí túmọ̀ sí pé kò sí oníṣẹ́ ọnà kan tó lè gbé iṣẹ́ kalẹ̀ tán kí ó tún wá yọ kòmóòkun nínú iṣẹ́ tó gbé jáde Bí gbẹ́nàgbẹ́nà bá yọwọ́ tirẹ̀ tán á wá kù sọ́wọ́ gbẹ́nugbẹ́nu Báyọ̀ Adébọ̀ gbẹ́nàgbẹ́nà iṣẹ́ tí a fẹ́ ṣe gbẹ́nugbẹ́nu rẹ̀ ní ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n tí Báyọ̀ Adébọ̀ kọ Ṣè bí onírúurú ni aṣọ alágẹmọ onírúurú iṣẹ́ ìwádìí ni ó ti wáyé lórí ẹ̀yà lítíréṣọ̀ Yorùbá tí a mọ̀ sí eréoníṣe tí a mọ̀ sí eréonítàn nígbà tí ètò ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́nkọ mọ̀ọ́nkà dé Onírúurú àwọn onímọ̀ ni wọ́n ti ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀yà lítíréṣọ̀ Yorùbá tí a mọ̀ sí eréonítàn Lára àwọn ni; Adédèjì Ajíbóyè nínú ìwé rẹ̀ tí ó pè ní lítíréṣọ̀ Yorùbá Ìṣọ̀lá Ògúnbìyí nínú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Adédèjì ṣàlàyé nǹkan tí à ń pè ní eréoníṣe tẹ́lẹ̀ Iṣẹ́ ìsínjẹ tí a ṣẹ̀dá tí ó ní àsopọ̀ pẹ̀lú àṣà ẹ̀sìn àti èdè àwọn `enìyàn kan Adédèjì fi ń yéwà pé láti ibi ìsínjẹ ni eréoníṣe ti bẹ̀rẹ̀ àti wí pé nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ àwọn ọmọ ènìyàn ni wọ́n ń ṣe ìsínjẹ rẹ̀ Síwájú sí i gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé kí àwọn aláwọ̀ funfun tó mú ìmọ̀ mọ̀ọ́nkọ mọ̀ọ́nkà dé ni àwọn babańlá wa ti ní ìmọ̀ kíkún nípa oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ènìyàn lè gbé ìgbé ayé rẹ̀ kà èyí ló fún wọn ní òye àti ọgbọ́n inú láti lè ṣe àtúpalẹ̀ ìwé tàbí nǹkan mìíràn Nípasẹ̀ èyí ni ó mú àwọn ọmọ wọn náà ní ọgbọ́n inú láti le ṣe àtúpalẹ̀ Látàrí ọgbọ́n inú yìí ni ó mú kí a wo ọ̀nà tí òǹkọ̀wé gbà fi ṣe ìṣẹ́ àti ìyà hàn nínú ìwé eréonítàn tí Báyọ̀ Adébọ̀ pè ní Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ìwádìí yóò tẹ̀síwájú lórí ìṣẹ́ àti ìyà okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé ṣe fi hàn A pín iṣẹ́ ìwádìí yìí sí olóríjorí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan sì máa ni ohun tí a yẹ̀wò ní abẹ́ rẹ̀ Ní orí kìíní a sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí a fi fẹ́ gùnlé iṣẹ́ ìwádìí náà èyí tí a pè ní èrèdí iṣẹ́ ìwádìí Ní abala yìí ni a ti wo àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí ṣíṣe ọgbọ̀n tí a lò láti ṣe ìwádìí ètò àti ìlànà tí a fi ṣe ìwádìí Orí kejì iṣẹ́ yìí dálé aáyan àwọn ọ̀mọ̀ràn èyí tí ó túmọ̀ sí iṣẹ́ tí àwọn onímọ̀ tí ṣe lórí orí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí tàbí èyí tó jọ ọ́ Ní abala yìí ni a ti eréonítàn Bákan náà ni a ṣe àmúlò tíọ́rì Ṣosíọ́lọ́jì tí tẹ̀lé ìlànà ìlànà àti èrò ó jẹmọ́ ìbágbépọ̀ àwùjọ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé ìtúpalẹ̀ ìwé kò le kẹ́sẹjárí láìní ọwọ́ tíọ́rì nínú Ní orí kẹ́ta iṣẹ́ ìwádìí yìí ni a ti wo àhunpọ̀ ìtàn ibùdó ìtàn ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa ìṣẹ́ àti ìyà Bákan náà ni a ó wo okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà àti àtubọ̀tán rẹ̀ Lẹ́yìn èyí ni a ó ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ẹ̀dá ìtàn bí ẹni tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá jà Ní abala kẹ́rin ni a ti wo bí òǹkọ̀wé ṣe ṣàfihàn ìṣẹ́ àti ìyà Bákan náà ni a ó wo ìhà tí òǹkọ̀wé kọ si ìṣẹ́ àti ìyà nínú eréonítàn rẹ̀ Bákan náà ni a wo ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé ṣe fi hàn Orí karùnún tí ó jẹ́ abala tó gbẹ̀yìn nínú àwọn ìsọ̀rí tí a pín iṣẹ́ ìwádìí yìí sí ni àgbálọgbábọ̀ Ní abẹ́ ìsọ̀rí yìí ni a ti wo ìṣọníṣókí àbọ̀ ìwádìí Níbi ní a ti fẹnuba ọ̀kanòjọ̀kan ìsọ̀rí tí a fojú rí àléébù àti àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí Ní ìgbẹ́yìn ni a sọ̀rọ̀ nípa ìkádìí ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Ìdí pàtàkì tí a fi gùnlé iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti tan ìmọ́lẹ̀ sí ìṣẹ́ àti ìyà nínú ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n tí Báyọ̀ Adébọ̀ kọ Náání nàànì náání ohun a ní là á náání ọmọ aṣẹ́gità ń náání èpo igi Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé ọ̀kan lára ẹ̀yà lítíréṣọ̀ Yorùbá ni eré oníṣẹ́ tí a pè ní eréonítàn nígbà tí ó di kíkọ sílẹ̀ jẹ́ ó sì yẹ kí a mọ ipò tí ó wà ní agbolé lítíréṣọ̀ Yorùbá ní ayé àtijọ́ àti òde òní Yorùbá sì ní bí onígbá bá ṣe gbé igbá rẹ̀ ni a ṣe é bá a gbé é ó ṣe ni láànánú wí pé ìgbékúùgbé ni àwọn Yorùbá ń gbé eréonítàn tiwọn wọ́n ò kàásí nǹkan kan àṣà àtọ̀húnrìnwá ti gba làákàyè wọn Iṣẹ́ ìwádìí yìí á fún wa ní àǹfààní láti mọ okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà láwùjọ ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé oríṣìíríṣìí nǹkan ló ń ṣe okùnfà iṣẹ́ àti ìyà bí i àpọ̀jù ènìyàn àìtó oúnjẹ àti àìsí owó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ; iṣẹ́ ìwádìí yìí á fún wa ní àǹfààní láti mọ ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà Kókó mìíràn nípa iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti jẹ́ kí òye tó yè kooro yéni nípa òǹkọ̀wé Báyọ̀ Adébọ̀ gẹ́gẹ́ bí okùnfà iṣẹ́ ìwádìí tó jinlẹ̀ nípa ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n lẹ́yìn wá ọ̀la IBI TÍ ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní okùn kì í gùn kó máà ní òpin kò sí bí iṣẹ́ ìwádìí ti lè gbòòrò tó kí ó máà ní ibi tí ààlà rẹ̀ yóò mọ Gẹ́gẹ́ bí àkòrí iṣẹ́ yìí Ìṣẹ́ àti Ìyà nínú ìwe Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni a ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò eréonítàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan pàtàkì lára ẹ̀yà lítíréṣọ̀ Yorùbá àti oríṣìí ipa tí ìṣẹ́ àti ìyà ń kó láwùjọ Síwájú sí i iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò tún sọ nípa ìdìde àti Yorùbá àti ọjọ́ iwájú eréonítàn Lára nǹkan tí ó tún jẹ olùwádìí lógún jùlọ ni títan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé ṣe fi hàn àti ìhà tí àwùjọ kọ sí ìṣẹ́ àti ìyà Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà ni ó ti dé bá lítíréṣọ̀ Yorùbá tí ó sì mú kí ìṣòro wà fún jíjò geere iná eréonítàn Yorùbá Lára okùnfà wàhálà náà ni àwọn ìjọba Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iléìwé ni wọ́n ti ṣiṣẹ́ lórí èdè Yorùbá àti wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òǹkọ̀wé ni wọ́n ń bẹ̀rù lórí ìwé tí yóò kọ Irú àwọn ìṣòro yìí ni a ó ṣe àyẹ̀wò fínnífínní lé lórí láti wá ọ̀nà àbáyọ si wọn Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí a ó ṣe àgbéyẹ̀wò ìṣẹ́ àti ìyà nínú Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n tí Báyọ̀ Adébọ̀ kọ A ó gbìyànjú láti tan ìmọ́lẹ̀ sí nǹkan tí ó ṣokùnfà ìṣẹ́ àti ìyà láwùjọ Yorùbá ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá nípa ìṣẹ́ àti ìyà àti ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà gẹ́gẹ́ bi òǹkọ̀wé ṣe fi hàn A ó gbìyànjú láti ṣe àfiwé àwùjọ tí òǹkọ̀wé fihàn wá pẹ̀lú àwùjọ tí kò tí ì sí ìṣẹ́ àti ìyà bó ti wù kó mọ ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ Àìfigbe bọnu ni àìrí ẹni gbani Bẹ́ẹ̀ ni egúngún kì í ní atọ́kùn tán kó tún sìnà Oríṣìíríṣìí àwọn ìgbésẹ̀ ni a tẹ̀lé láti ṣe ìwádìí lórí kókó iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí láti ní òye kíkún lórí iṣẹ́ yìí A ṣe akitiyan láti ṣe ìwádìí lọ́wọ́ onírúurú ènìyàn pàápàá jùlọ òǹkọ̀wé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n fún àbáyọrí tó yè kooro lórí àpilẹ̀kọ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní a kì í fá orí lẹ́yìn olórí Èyí ló fún wa ní àǹfààní láti mọ ìdí pàtàkì tí ó mú un kọ ìwé náà àti àkọlé tí ó fún un Síwájú sí i a lo ìlànà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò oníbéèrè A lo ẹ̀rọ agbohùnsílẹ̀ láti fi gba ohùn abẹ́nàìmọ̀ sílẹ̀ láti fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ìbéèrè tí a bi wọ́n Síwájú sí i kí a tó lọ bá abẹ́nàìmọ̀ a ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìbéèrè tí a ó béèrè lọ́wọ́ wọn kí a bá à máà fi àkókò wọn sòfò Lára ọgbọ́n tí a ṣe àmúlò rẹ̀ ni lílọ sí iyàrá ìkówésí láti lọ wo ọ̀kanòjọ̀kan ìwé lórí iṣẹ́ ìwádìí yìí kí ó ba lè tọ́ wa sọ́nà Bákan náà ni ẹ̀rọ ayélujára kò gbẹ́yìn nínú ọgbọ́n ìwádìí tí a ṣe àmúlò Nítorí àwọn aláwọ̀ funfun ti sayé dẹ̀rọ̀ nípa ẹ̀rọ ayélujára ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Ní tòótọ́ eréonítàn kó ipa tí ó jọjú láwùjọ Yorùbá èyí tí ó sì jẹ́ pé nípasẹ̀ àwọn òǹkọ̀wé eréonítàn ni ìdàgbàsókè àti ìgbà ọ̀tun ṣe dé bá eréonítàn lédè Yorùbá Iṣẹ́ ìwádìí yìí á jẹ́ kí a mọ̀ wí pé ọlá àbàtà ló ń módò sàn ọlá àwọn òǹkọ̀wé ni kò jẹ́ kí àwọn ìtàn ìṣẹ̀ǹbáyé di ohun ìgbàgbé Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé tí a bá wo àwùjọ wa lónìí ìṣẹ́ àti ìyà jẹ́ nǹkan tí ó wọ́pọ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí a fún wa ní àǹfààní láti mọ okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà àti ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà Tí a bá wo eréoníṣe láyé àtijọ́ a ó rí i wí pé ọ̀kan pàtàkì ló jẹ́ lára lítíréṣọ̀ Yorùbá Iṣẹ́ ìwádìí yìí a jẹ́ ki a mọ ìdìde àti ìdàgbàsókè eréonítàn Yorùbá Ní àkótán iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí yóò wúlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ iwájú tí yóò wúlò fún àwùjọ láti mọ ọ̀nà àbáyọ fún ìṣẹ́ àti ìyà á wúlò fún òǹkọ̀wé láti lè mọ àléébù àti àmúyẹ iṣẹ́ rẹ̀ Iṣẹ́ ìwádìí yìí a wúlò fún àwọn olórí ìjọba ìlú láti lè wá ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ tí ó ń bá àwọn ènìyàn jà Bákan náà ni a ó wo ipa tí ìṣẹ́ àti ìyà ń kó láwùjọ ipa rẹ̀ lórí àwọn ẹgbẹ́ gbogbo ipa rẹ̀ lórí àwùjọ bákan náà ni a ó ṣe àgbéyẹ̀wò ipa ìṣẹ́ àti ìyà lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ÈTÒ ÌWÁDÌÍ Èròǹgbà iṣẹ́ yìí ni láti wo ìṣẹ́ àti ìyà nínú ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n tí Báyọ̀ Adébọ̀ kọ Kò sí nǹkan náà ní ilé ayé tí kò ní ìlànà tàbí ètò tí ó tẹ̀lé A pín iṣẹ́ ìwádìí yìí sí ọ̀nà márùnún àkọ́kọ́ dálé ìpilẹ̀sẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí a ṣe ìfáàrà lórí ohun tí ó pilẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí Nínú rẹ̀ ni a ti sọ èrò ọkàn olùwádìí ní pàtó tí ó fi yan iṣẹ́ ìwádìí yìí láàyò Ìṣẹ́ àti Ìyà nínú ìwé Eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n A tún wo ibi tí ìwádìí gbòòrò dé ọgbọ́n ìwádìí àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí nígbà tí ètò ìwádìí náà kò gbẹ́yìn Ní orí kejì ni a ti ṣe àgbéyẹ̀wò aáyan ọ̀mọ̀ràn èyí tí ó túmọ̀ sí iṣẹ́ àwọn asíwájú lórí orí ọ̀rọ̀ yìí tàbí èyí tí ó fara pẹ́ ẹ Bákan náà ni a ṣe àgbéyẹ̀wò eréonítàn Yorùbá bẹ́ẹ̀ náà ni a ó ṣe àmúlò tíọ́rì Ṣosíọ́lọ́jì Lítíréṣọ̀ to tẹ̀lé ìlànà àti èrò í orí kẹ́ta ni a ó ti wo àhunpọ̀ ìtàn ní ṣókí okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà láwùjọ ibùdó ìtàn bí ó ṣe ṣe àfihàn ìṣẹ́ àti ìyà bákan náà ni àwùjọ tí ó bí ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n náà kò ní gbẹ̀yìn Ní àfikún nínú orí kẹ́rin ni a ó ti sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ́ àti ìyà láwùjọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà ìhà tí òǹkọ̀wé kọ sí ìṣẹ́ àti ìyà nínú ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n ìlò èdè òǹkọ̀wé bí ó ṣe fi ìṣẹ́ àti ìyà hàn Ní àkótán orí karùnún iṣẹ́ yìí dá lórí àgbálọgbábọ̀ fún gbogbo iṣẹ́ ìwádìí tí a ṣe pẹ̀lú àkọsílẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí láti òkè títí dé ilẹ̀ A tún ṣe ètò fún àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí tí a sì lo ìkádìí fún ìparí iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN ÌFÁÀRÀ Ní abala yìí ní a tí ṣàgbéyẹ̀wò iṣẹ́ tí o tí wà sáájú tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àkọ́rí iṣẹ́ yìí Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ipa abéẹ́rẹ́ ni otun ń tọ àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ asíwájú yìí ni yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ ti a máa tẹ̀ lé òun ti yóò tọ́ wa sọ́nà láti mo ìbí ti ọ̀rọ̀ dé dúró àti ibi tí ọ̀rọ̀ kì í sí Àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ ìwádìí yìí ni yóò sọ ìyàtọ̀ láàárín iṣẹ́ ti a ṣe àti èyí tó ó tí wà nílẹ̀ tẹ̀lé rí Ní abala yìí ní a o ti wo lítíréṣọ̀ àti àwùjọ okùnfà ìṣẹ́ àti ìyá ìhà tí àwùjọ kọ sí ìṣẹ́ àti ìyá ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyá nígbà tí tíọ́rì ìṣàmúlò kò ni gbẹ̀yìn ni bala yìí náà LÍTÍRÉṢỌ̀ ÀTI ÀWÙJỌ ERÉONÍTÀN YORÙBÁ Nígbà ti a bá ń sọ̀rọ̀ nípa lítíréṣọ̀ àti àwùjọ nǹkan tí a ń tẹpẹlẹ mọ́ nì ìsafìhan àwùjọ nípa ọ̀nà tí àwọn ènìyàn àwùjọ gbà ń gbé ìgbé ayé wọn Lítíréṣọ̀ ni asàwòta àwùjọ lítíréṣọ̀ ni irinṣẹ́ ìwàásù àti ohun èlò tí o le tan ìmọ́lẹ̀ kalẹ̀ tí a le fi ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ nípa ohun tí o ń ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ ayé Èyí farapẹ́ èrò Rees tí o sọ bàyìí pé lítíréṣọ̀ ní àkọsílẹ̀ ti ń ṣàlàyé àti ìgbéjáde èrò ìmọ̀lára àti ìhà ti a kọ sí ilé ayé Lítíréṣọ̀ ni aṣàfihàn àwùjọ ìbá a ṣe ewì eréonítàn ìtàn àròsọ inú àwùjọ ni a ti ń rí èròjà tí a ń lò bákan náà inú àwùjọ ni a ti kò èròjà náà ti a lò tí o fi di odindin jọ Àti pàápàá òǹkọ̀wé tí o kọ ìwé kò jábọ́ láti inú àwùjọ ni o tí rí ọgbọ́n ìmọ̀ àti òye ti o lò láti gbé lítíréṣọ̀ kalẹ̀ Adéyẹmí sọ nínú ìwé rẹ̀ o ni; Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa lítíréṣọ̀ náà ohun ti jẹmọ́ ọmọnìyàn àti àwùjọ lọ dálé Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìtàn tí òǹkọ̀wé ń kọ sí in eré onítàn lónìí lọ jẹ́ èyí tí o ti ṣẹlẹ̀ ní àwùjọ sẹ́yìn tàbí àwọn èyí ti o ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ lọ́wọ́ láwùjọ Bákan náà ni a le sọ wí pé ọ̀nà ibaraẹní sọ̀rọ̀ ni lítíréṣọ̀ o le wádìí ẹ̀dá jinlẹ̀ lítíréṣọ̀ le mọ nípa rẹ ibi ti o ń gbé ganan fún ìdí èyí a le sọ wí pé ajólórí lítíréṣọ̀ ní àwùjọ Àwùjọ ní ìbí tí àwọn ènìyàn ń gbé àti ọ̀nà tí wọn ń gbà gbé ìgbé ayé wọ́n Ìwà wọ́n iṣẹ́ wọn ijẹnu wọn ìwọsọ wọn ọ̀nà tí wọn ń gbà láti bá ara wọn sọ̀rọ̀ tí o jẹ́ èdè gẹ́gẹ́ bí òpómúléró àṣà àti iṣẹ́ àwùjọ kan Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí la ń wo mọ àwùjọ ti a fi ń pé àwùjọ ni àwùjọ Àjàyí ṣàlàyé pé kò sí ẹ̀yà tí kò ní àṣà àti ìṣẹ̀ṣe tiwọn Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tí ó wà ní ayé ni o ní ìṣẹ̀ṣe tirẹ̀ láìdéènà pẹnu díẹ̀ nínú àwọn nǹkan tí ó parapọ̀ jẹ́ àwùjọ ni èrò ìgbàgbọ́ ìmọ̀ ìkíni Ní àgbáyé kò sí ẹ̀yà tàbí àwùjọ tí kò ní àṣà àti ìṣẹ̀ṣe tìwọn àṣà àti ìṣẹ̀ṣe yìí yàtọ̀ láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà mìíràn Ṣùgbọ́n nǹkan tí o jẹ gbogbo wọn lógún ni láti ṣe àfihàn àwùjọ wọn Fún ìdí èyí a lè sọ wí pé àti lítíréṣọ̀ àti àwùjọ nǹkan tí o jẹ́wọn lógún jù ní láti ṣe àfihàn àwùjọ Bákan náà ní a tún le pé e ní ìrírí àwùjọ nípa ara wọn ilé ayé wọn Nítorí náà àtinúdá ti a wà nínú rẹ̀ ni lítíréṣọ̀ àti àwùjọ jẹ́ Èyí fi hàn pé ti a bá fẹ́ mọ nípa àwùjọ a gbúdọ̀ mọ àwùjọ náà àti lítíréṣọ̀ ti o ń jáde ni àwùjọ sọ pé Láìsí ẹ̀rí kíkún àwọn onímọ̀ iṣẹ́ àtinúdá ẹ̀rí àwọn to ń kò nípa àwùjọ kò tì i lè kun tó Èyí ti hàn pé lítíréṣọ̀ ṣe pàtàkì tí a bá fẹ́ mọ nípa àwùjọ kan Pẹ̀lú àkíyèsí yìí a lè sọ wí pé àti lítíréṣọ̀ àti àwùjọ ọmọ ìyá kan náà ni wọ́n tí wọn sí máa ń ba ara wọn ṣíṣe pọ Kò sí bí a ṣe máa porí ajá ti a o ni pórí ìkòkò tí a fi ṣe e ni lítíréṣọ̀ àti àwùjọ rí sí ara wọn Fún ìdí èyí kò sí bí a ṣe máa pórí lítíréṣọ̀ ti a o ní porí àwùjọ tí irú lítíréṣọ̀ bẹ́ẹ̀ ti jáde Gẹ́gẹ́ bí ṣe sọ A lè mọ nípa ìran kan daada bí a ba farabalẹ ka lítíréṣọ̀ irú ìran tàbí orílẹ̀ èdè bẹ́ẹ̀ Fún ìdí èyí kò sí bí a ṣe máa yọ̀wọ́ lítíréṣọ̀ kúrò nínú àwùjọ nítorí ọla àbàtà ló ń módò sàn ọlá bàbá ọmọ lọ ń mọmọ yan ní lítíréṣọ̀ àti àwùjọ OKÙNFÀ ÌṢẸ́ ÀTI ÌYÀ LÁWÙJỌ Oríṣìíríṣì nǹkan lọ máa ń ṣe okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà ṣùgbọ́n kí a tó lọ sí okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà kí ní a ń pè ní iṣẹ́ àti ìyá fún ra ra rẹ Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹnìkan kí ìṣẹ́ àti ìyà báyìí ìṣẹ́ àti ìyá ní kí ènìyàn máa rí nǹkan tí o fẹ bí omi tó dára ilé ìwòsàn ilé ìwé ọ̀nà méjì ni a le gbà wo iṣẹ́ ìkììńí àìlè pèsè nǹkan àti àìní nǹkan tó Ìṣẹ́ ló máa ń di ìyà Ìṣẹ́ ni kí ènìyàn máa rí nǹkan tí ó fẹ́ ní àsìkò tí o wù á nípasẹ̀ àìrí owó láti ràá Àpọ̀jù ìṣẹ́ ló máa ń di ìyà Ní àgbáyé lónìí kò sí ẹ̀yà tàbí àwùjọ ti ìṣẹ́ àti ìyà kò tí máa bá wọn fínra Nínú èrò Gomina ìpínlẹ̀ Eunju nígbà kan rí ṣe sọ nígbà ti wọ́n pé é kí ó wá sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ àṣekágbá tí ẹlẹkẹdogun ní ni ọjọ kẹfà oṣù kẹwa ọdún Ó ṣàlàyé pé ni ọdún laaa ida mẹ́talelọgọrin nínú ògún àti ọgọ́rùnún ní ìṣẹ́ àti ìyà ń ba ja Ó tẹ̀síwàjú láti ṣàlàyé pé ni ayé àtijọ́ wọn máa ń sọ wí pé àwọn ìlú ìgbèríko ní ìṣẹ́ àti ìyà ti máa ń wáyé látàrí àwọn nǹkan bí i àìní oúnjẹ tí o dára omi tí kò dára àìní ina àti àìní owó láti rán ọmọ lọ sí ilé ìwé O wa sọ wí pé títí di òní náà ní nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀ O ṣàlàyé wí pé ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀ láti ibi àìní iṣẹ́ òní ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀ láti ibi àírísẹ́ tàbí àìní nǹkan láti fi sisẹ́ Oríṣiríṣi nǹkan ni o ń ṣe okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà ni àwùjọ lára àwọn nǹkan náà ni àpọ̀jù ènìyàn Àìní iṣẹ́ ilé ìwé tí kò dára to ètò olókòwò aládàńlá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ i Àpọ̀jù Ènìyàn Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan pàtàkì lára okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà ni àwùjọ túmọ̀ sí wí pé kí ènìyàn pọ ju nǹkan ti a ń pèsè lọ èyí túmọ̀ sí pé kó sí oúnjẹ tópọ̀ bẹ́ẹ̀ sin àyè náà o pọ to Èyí lọ mú kí ẹnìkan ṣàlàyé pé Àpọ̀jù ènìyàn pẹ̀lú nǹkan tì kò pọ àti ààyè díẹ̀ ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ àti ìyá Bákan náà ní wọ́n tún tẹ̀síwàjú láti ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀èdè ti o wa ní àgbáyé lónìí ní ìṣẹ́ àti ìyá ń bá fínra látàrí àpọ̀jù ènìyàn wọ́n fi kun wí pé àwọn ìlú bí i tí wọn ní òun èlò àpọ̀jù ènìyàn kó ní ó jẹ́ orísun ìṣẹ́ àti ìyá tiwọn nítorí wọn ní oúnjẹ tí o pọ tí o le tó wọn jẹ Ṣùgbọ́n síbẹ̀ náà ìṣẹ́ àti ìyá ń ba wọn fínra Bákan náà ni iṣẹ́ àti ìyá le wáyé nípa ètò ọ̀gbìn tí kò fara rọ Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ kan ṣe fi hàn tí a ba wo àwọn ìlú bí i fún àpẹẹrẹ àwọn ní o jẹ ọ̀kan lára ẹ̀yà tí o pọ ju ní àgbáyé Àkọsílẹ̀ náà fi yéni pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ènìyàn ìlú náà ni ìṣẹ́ àti ìyá ń ba fínra ọ̀pọ̀ nínú àwọn ènìyàn ní ni wọnn ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ pẹ̀pẹ̀pẹ́ èyí sí mú kí iṣẹ́ àti ìyá orílẹ̀ èdè náà peléke Nítorí náà ní àgbáyé lónìí kò sí orílẹ̀ èdè ti ìṣẹ́ àti ìyá kò ti wọ́pọ̀ látàrí àpọ̀jù ènìyàn Ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ọdún àwọn ènìyàn ti iṣẹ́ àti ìyá ń baja jẹ ida mẹ́fà nínú ọgọ́rùnún nítorí náà bí ènìyàn ṣe ń pọ sí bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ àti ìyá náà ń pọ sí yika ní orílẹ̀ èdè àgbáyé ÀÌRÍ IṢẸ́ ṢE ẹnìkan ṣàlàyé pé; àìrí iṣẹ́ lọ máa ń yìí sí iṣẹ́ àti ìyá Ní àgbáyé lónìí àìrí iṣẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára nǹkan tí o ń ṣe okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà nítorí ti oníkálùkù ba ní iṣẹ́ lọ́wọ́ ìṣẹ́ àti ìyá a dínkù tí iṣẹ́ àbá sí ti dín ku ni ìwà aidara gbogbo ni àwùjọ náà a din ku Ọ̀pọ̀ ènìyàn ti o fẹ ṣisẹ́ láti bọ́ àwọn ẹbí wọ́n ni wọ́n ò rí iṣẹ́ Ìṣòro àìrí iṣẹ́ yìí jẹ́ èyí tí o wa ní gbogbo orílẹ̀ èdè ni àgbáyé Nínú àlàyé ẹnìkan o sọ pé Ju mílíọ́ọ́nù ènìyàn tí wọn tó sisẹ ní wọn ò rí iṣẹ́ iii ÀPỌ̀JÙ OWÓ ILÉ Èyí wáyé látàrí àjò olókòwò aladanla tí o gba orílẹ̀ èdè kan pàápàá ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà Èyí wáyé nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ìlú tí wọn lórúkọ ti ọ̀rọ̀ ajé ti wa níbẹ̀ ní owó ilé wọ́n tí ọ̀pọ̀ ènìyàn kò sí ní àǹfààní láti rówó gba irú ilé bẹ́ẹ̀ Ẹnìkan ṣàlàyé wí pé ẹní tí wọ́n ń san owó oṣù fu tí o dára fún ganan wí pé ọ̀pọ̀ wọn ni kò le ra aṣọ àti oúnjẹ ti o dára nítorí owó rẹ̀ ti pọ̀jù Ní àwọn àyé laan kódà àwọn ènìyàn tí wọn ni iṣẹ́ tí wọn sí ń san owo fún ní wọn le máa le borí ìnáwó wọn ILÉ ÌWÉ TI KÒ KÚN OJÚ ÒṢÙWỌ̀N Èyí náà jẹ́ ọ̀kan lára okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wọn o le lọ ilé ìwé ti o dára Tí èyí bá ríbẹ àti rí iṣẹ́ yóò sọ̀rọ̀ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní a gbé ìwé èrí lọ́wọ́ tí wọn o sí ni le ṣàlàyé rẹ̀ nítorí èyí kò ni rí iṣẹ́ ìṣẹ́ àti ìyà a sí máa peléke sí Ẹnìkan ṣàlàyé pé ni wí pé o ọ̀pọ̀ ènìyàn ní wọn o lọ ilé ìwé tí ó dára Nínú àwọn ọmọ tí wọn wa ni ida ọgọta nínú ọgọọrun lọ kawe tí kò pọ laisí sí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò le ní iṣẹ́ tí yóò máa tí máa rí owó Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ló ṣokùnfà ìṣẹ́ àti ìyà ní àwùjọ Gbogbo ìjọba ní orílẹ̀ èdè ni àgbáyé lọ tí gbé ètò kalẹ̀ láti le ìṣẹ́ àti ìyà jìnnà Bí àpẹẹrẹ ní ìpínlẹ̀ Èkó àwọn obìnrin gbé ètò kan kalẹ̀ tí wọn pé ni wọ́n gbé ètò yìí kalẹ̀ láti máa ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ nípa kókó iṣẹ́ ní èyí ti adín iṣẹ́ àti ìyá kù Bákan náà ní wọn da àwọn ètò kalẹ̀ lọ́kàn o jọ̀kan láti gbogun tí iṣẹ́ àti ìyá bí ÌHÀ TÍ ÀWÙJỌ KÒ SÍ ÌṢẸ́ ÀTI ÌYÁ Ìran Yorùbá jẹ́ ìran tí o fẹ́ràn iṣẹ́ ṣíṣe wọn ò fààyè gba ọ̀lẹ àti ìmẹ́lẹ́ wọ́n kórìíra rẹ̀ ganan nítorí wọn gbàgbọ́ wí pé ẹní ti kò bá ṣiṣẹ́ yóò jalè Àti wí pé Yorùbá fúnka mọ́ ìwà ọmọlúàbí nítorí ẹní tí o ba tí jale tí ba ọmọlúàbí rẹ̀ jẹ́ Ọ̀pọ̀ nínú òwe wọn ló fi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ èrò wọn nípa títẹpá mọ́ iṣẹ́ àti títako ìwà ọlẹ hàn lára àwọn òwe náà nìwọ̀nyí i Bí ọ̀lẹ o ku ẹ jẹ́ o ku àìkú ọ̀lẹ̀ kò da nǹkan ii Ọyẹ́ ni yóò kìlọ̀ fún onítòbí Ẹbí ni yóò kìlọ̀ fún ọ̀lẹ̀ iii Ààlà ni yóò foko ọ̀lẹ hàn Iṣẹ́ jàre ọ̀lẹ bí oyé ti ń jàre òru Àwọn òwe wọ̀nyí fi ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa ìwà ọ̀lẹ hàn wọn o ka wọ́n sí ni àwùjọ wọn máa ń téńbẹ́lú wọn láwùjọ Ògúnníran sọ nípa ọlẹ pé Alapa máa ṣiṣẹ́ ọmọ òkú ọ̀lẹ bénìyàn o nísẹ́ lọ́wọ́ olúwrẹ̀ yíò jẹ̀bi ọba Bènìyàn ò níṣẹ́ lọ́wọ́ olùwarẹ̀ yio jẹ̀bi ìjòyè iṣẹ́ ni ó gún ìṣẹ́ Yorùbá jẹ́ ẹ̀yà kan tí o tako ìwà ọ̀lẹ Ìdí ti wọ́n fi ń ṣe èyí ní pé bí ẹní kọ̀ọ̀kan bá ní iṣẹ́ lọ́wọ́ iṣẹ́ àti ìyá yóò jínà sí àwùjọ bẹ́ẹ̀ Àlàyé fi hàn pé ṣáájú òmíràn ìṣẹ́ àti ìyà kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pò láwùjọ àti lẹ́yìn òmíràn ti ìwọ́ká bẹ̀rẹ̀ Migeration bẹ̀rẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sí ń fi iṣẹ́ abínibí wọn sílẹ̀ ti wọ́n sí ń lọ sí ìlú ńlá ńlá láti lọ máa wa iṣẹ́ òòjọ́ mìíràn Bákan náà nígbà ti ọ̀làjú bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹ u tí ètò olókòwò aladanla bẹ̀rẹ̀ Àkíyèsí fi hàn pé àwùjọ Yorùbá ti ń dàrú tí oníkálùkù sí bẹ̀rẹ̀ sí ni sare owó Ṣùgbọ́n bí àwọn wọ̀nyí tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ àwùjọ Yorùbá ń fi ìkórìíra wọn hàn sí ìṣẹ́ àti ìyà Ìdí nìyí tí wọn o fi máa ń tenpẹlẹ mọ iṣẹ́ abínibí wọn èyí ló fi èrò wọn hàn wí pé bí ebi bá kúrò nínú ìṣẹ́ ìṣẹ́ bù ṣe Fálétí sọ pé; Iṣẹ́ ẹní ni iṣẹ́ ẹní ma tijú iṣẹ́ rẹ̀ Bígi lo bá ń ké dowó bí wọn gba ọ́ pé kò wa gbálẹ̀ lọ́jà iṣẹ́ ẹni ni iṣẹ́ ẹni Yorùbá fẹ́ràn kí ènìyàn máa ṣiṣẹ́ kí ènìyàn sí máa korira nítorí olòsì òní ń bọ wá dolówó bo dọ̀la Wọn gbàgbọ́ wí pé ti gbogbo ènìyàn ba ń ṣíṣe iṣẹ́ àti ìyá tí o gbode kan yóò dínkù Kò sí àwùjọ ti o fẹ́ràn ìṣẹ́ àti ìyà nítorí èyí ni àwọn ìjọba ṣe gbé ètò kalẹ̀ wọ́n pé ni ètò didẹkun iṣẹ́ àti ìyá fún gbogbo àwùjọ ní ọdún kókó ètò wọ̀nyí ni láti sọ ìṣẹ́ àti ìyà di ohun ìgbàgbé Yorùbá jẹ́ ẹ̀yà tí o kórìíra ìṣẹ́ àti ìyà nítorí wọn gbá wí pé ìṣẹ́ máa ń pa ènìyàn wọn fi ìdí èyí múlẹ̀ nígbà tí wọ sọ wí pé iṣẹ́ tí o ṣe ọmọ fún ògún ọdún tí kò ba pa ọmọ a dẹ̀yìn lẹ́yìn ọmọ Ọ̀NÀ ÀBÁYỌ KÚRÒ NÍNÚ ÌṢẸ́ ÀTI ÌYÁ Ní ọdún Báǹkì àgbáyé là á mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà jẹ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè tí o ní ọrọ̀ajé púpọ̀ ni àgbáyé síbẹ̀ ìṣẹ́ àti ìyà ti pa kádàrá orílẹ̀ èdè náà da sí òmíràn tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ń rá re nínú ìṣẹ́ àti ìyà Ni ọdún ẹ̀ka tó ń mójú tó ọ̀rọ̀ ìwádìí lórí ètò ọrọ̀ajé ni Báǹkì ti ó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ìyẹn fi hàn pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ rí ni nǹkan bí sí Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan lára orílẹ̀ èdè to lówó jù lágbàjáyé látàrí àwọn eré to ń jáde lára ètò ọ̀gbìn Gasi àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun àmúsọrọ̀ to ń bẹ lálẹ́ ilẹ̀ Ṣùgbọ́n ni báyìí Nàìjíríà jẹ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀èdè bí i mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí ìṣẹ́ àti ìyà ń ba fínra ni àgbáyé Ìwádìí fi hàn ní ọdun pé nínú ìdá mẹ́wàá ìdá mẹ́fà ni ọwọ́ ìṣẹ́ àti ìyà wà lára wọ́n ṣùgbọ́n nígbà tí yóò fi di ọdún ìwádìí fi hàn pé ìdá méje nínú mẹ́wàá ni ìṣẹ́ àti ìyà ti ń ba fínra Wọn sọ Ní ọdún ìṣẹ́ àti ìyà tí tún pọ di ìdá àádọ́rin nínú ìdá ọgọ́rùnún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ní wọn tí gbìyànjú láti wa ọ̀nà àbáyọ sí iṣẹ́ àti ìyá láwùjọ Ọbadán nínú iṣẹ́ rẹ̀ fi hàn pé sáájú kí ìjọba Obasanjọ to gbé ètò lẹ́sẹ lugbẹ́ díde ní ọdún àti kò sí irú ètò báyìí to tí da dúró òun tí a máa ń rí ni àgbékalẹ̀ àwọn ìgbìmọ̀ tí ìjọba máa ń lọ láti wa ọ̀nà àbáyọ sí wàhálà ìṣẹ́ àti ìyà ni orílẹ̀èdè yìí Ọbadán fi èrò yìí hàn báyìí Títí dí ìgbà tí wọn gbé ètò lesẹ lùgbẹ́ kalẹ̀ labẹ́ ìjọba Nàìjíríà ní gbogbo ìgbìyanjú wọn láti le iṣẹ́ lùgbẹ́ lọ jẹ́ èyí tí wọn ń ṣe ni pàjáwìrí Ọbadán ṣàlàyé pé nǹkan tí o máa ń sábàá jẹ ìgbìmọ̀ yìí lógún ní láti rí eré rẹpẹtẹ nínú ọjà tí wọn ba tà sí òkè okun Ṣùgbọ́n ní èrò Ọbadán ni tirẹ̀ kì í ṣe eré tí wọ́n ba rí lọ ṣe kókó bí kò ṣe bí a ṣe ṣàmúlò eré yìí láti mú ìgbé ayé ìrọ̀rùn ba àwọn ènìyàn àwùjọ O wá ṣàlàyé síwájú sí pé àilè séése àwọn ìgbìmọ̀ yìí lọ fa iṣẹ́ àti ìyá tí o pọ̀ ní àwùjọ Ọbadáń gbàgbọ́ pé nǹkan tí a bá pé ní ètò lẹsẹ dùgbẹ́ kúrò láwùjọ gbọdọ̀ lè jẹ́ ohun tí yóò rọ eegun sí ènìyàn lápá Ó wá ṣàlàyé pé ọ̀nà tí a le gbà kúrò nínú ìṣẹ́ ni wí pé kí ìjọba rí wí pé gbogbo eré yòówù tí wọn bá rí lórí ètò ọrọ̀ajé gbọdọ̀ jẹ́ ohun èlò láti mú ìgbé ayé ìrọ̀rùn bá àwùjọ Ó ní Ìdàgbàsókè kì í ṣe kíkọ́ iye eré tí a rí sílẹ̀ o ṣe é ṣe kí a kọ èrè tí o pọ sílẹ̀ nígbà tí iye àwọn ènìyàn ti ìṣẹ́ àti ìyà ń ba fínra peléke ti wọn sí ní àwọn nǹkan amáyédùn Ohun kan tó ṣe pàtàkì ní láti mú ìgbé ayé ìgbádùn ba gbogbo ènìyàn kí Nàìjíríà le rí àyípadà rere nínú ìgbé ayé wọn Ní ọdún ìjọba Ọbásanjọ́ ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ ìṣẹ́ àti ìyà to ń wọ ènìyàn lára yìí jẹ ẹdùn ọ̀kan fún òun O ṣe àkíyèsí pé tí a ò bá tètè wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí o ṣe é ṣe kí nǹkan polúkúrúmusu jù báyìí lọ Ìdí nìyí tí ó fi gbé àwọn ètò kan kalẹ̀ bí ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún gbogbo ènìyàn àti ètò lesẹ lúgbẹ̀ láti wá ọ̀nà àbáyọ sí ìṣẹ́ àti ìyà ní àwùjọ Àbájáde èrò àti Ìgbìmọ̀ lórí bí a ṣe le gbogun ti iṣẹ́ àti ìyá ṣàlàyé pé Láti ìgbà tí ìjọba Ọbásanjọ́ tí gorí àléfà ni oṣù karùnún ọdún ní o tí ni èròǹgbà to jinlẹ̀ lórí bí ètò ìṣẹ́ àti ìyà ṣe ń paléke sí i ni Nàìjíríà Lára àwọn nǹkan tí o kókó ṣe ni láti da ilé ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ sílẹ̀ tí o pé ni àti ríran àwọn ìgbìmọ̀ lẹ̀sẹ̀ẹ́ lùgbẹ́ lọ́wọ́ Lára ètò tí ìjọba gbé kalẹ̀ láti wa ojutu sí ọ̀rọ̀ ìṣẹ́ àti ìyà yìí ni ètò dídẹ̀kùnún ìṣẹ́ àti ìyà fún gbogbo àwùjọ dá ètò yìí sílẹ̀ láti polongo ìṣẹ́ àti ìyà de ìgbèríko láti rí pé ìgbé ayé ìrọ̀rùn bá wọn Àwọn tí o jẹ alága ètò náà ni wọ́n tún jẹ olùdarí wọn Àwọn náà ní Joda àti èròǹgbà ìgbìmọ̀ wọn nípa wíwá ọ̀nà àbáyọ sí ìṣẹ́ àti ìyà nìyí Láti rí wí pé wọ́n pèsè ohun èlò iṣẹ́ fún àwọn obìnrin ọ̀dọ̀ àgbẹ̀ àti àwọn àkàndá ènìyàn Láti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí a o ti máa kọ́ nípa iṣẹ́ ọwọ́ loríṣiríṣi èyí tí yóò sí mú ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn nísẹ lọ́wọ́ kí wọn sí le dá dúró funra wọn Láti wá ọ̀nà sí bí wọn yóò ṣe máa ta erè oko ti ó ń jáde lorílẹ̀ èdè yìí nípa báyìí àwọn ènìyàn a le kọjú mọ iṣẹ́ àgbẹ̀ yóò sí ran àgbẹ̀ tí ó wà ní ìgbèríko lọ́wọ́ láti rí ọjà wọn tà Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni wọn gbé kalẹ̀ láti wá ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà ní àwùjọ Síwájú sí i lára ọ̀nà tí a tún le gba kúrò ni ìṣẹ́ àti ìyà ní pípèsè iṣẹ́ fún ọ̀dọ̀ fífí ètò sí ọmọ bíbí ríran àwọn àgbẹ̀ lọ́wọ́ nípa fífún wọn ní ajẹ́lẹ̀ pípèsè ilé ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tó ó dára fún àwọn tálákà kí àwọn náà le jẹ ènìyàn lọ́jọ́ iwájú Nípa ṣíṣe eléyìí ìṣẹ́ àti ìyà yóò dí ohun ìgbàgbé láwùjọ TÍỌ́RÌ ÌṢÀMÚLÒ TÍỌ́RÌ SOṢÍỌ́LỌ́JÌ LÍTÍRÉṢỌ̀ TÍ Ó TẸ̀LÉ ÌLÀNÀ ÀTI ÈRÒ Ìwádìí yòówù tí kò bá gùnlé tíọ́rì òfútùfẹ́tẹ̀ẹ́s ni Tíọ́rì dàbí abẹfẹ́lẹ́ ìmọ̀ tí a fi ń la ìfun àti ẹ̀dọ̀ iṣẹ́ kan Nínú ìmọ̀ sayensí ní tíọ́rì ti jẹyọ Ọbafẹ́mi kí tíọ́rì báyìí pé Tíọ́rì ní irinṣẹ́ ìmọ̀ nípa ẹwà lítíréṣọ̀ láti jẹ́ kí ìbáṣepọ̀ ó wà láàárín ìran òǹkọ̀wé imọọse rẹ̀ àti ìbánisọ̀rọ̀ tó péyé Ohun tí Ọbafẹ́mi ń sọ ni pé ohun èlò fún àlàyé lórí lítíréṣọ̀ ní tíọ́rì gbogbo ìmọ̀ ọgbọ́n àti òye òǹkọ̀wé kò le di mímọ́ láì lo tíọ́rì Oríṣiríṣi tíọ́rì ni ó wà bí i tíọ́rì ìfojú ààtò wo tíọ́rì ìfojú ìhun wo tíọ́rì ìfojú ìmọ̀ìbáraẹnígbépọ̀ láwùjọ wo tíọ́rì ìfojú àṣà ìbílẹ̀ wo tíọ́rì Ìṣègbèfábo tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì tí o tẹ̀lé ìlànà àti èrò tíọ́rì ìtàn ìgbésí ayé òǹkọ̀wé tíọ́rì Asàtakò Ìmúnisìn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ṣùgbọ́n nínú gbogbo àwọn tíọ́rì wọ̀nyí tíọ́rì tí o tẹ̀lé ìlànà àti èrò ni a máa ṣe àmúlò Àwọn agbátẹrù tíọ́rì yìí gbà pé ohun èlò tí àwùjọ lè fún ìjàgbara àwùjọ ní iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ jẹ́ Adéyẹmí ṣàlàyé pé Àwọn onímọ̀ tí o tẹ̀lé èrò rí iṣẹ́ aláwòmọ́ bí i ohun èlò ìjàgbara Tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì to tẹ̀lé ìlànà àti èrò kì í ṣe tíọ́rì òní o tí pẹ tí ó tí bẹ̀rẹ̀ olùdádsílẹ̀ tíọ́rì yìí ní orúkọ rẹ̀ ní àwọn agbátẹrù tíọ́rì náà fi ń pè é Láti nǹkan bí i ọdún ni fúnra rẹ̀ tí ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí àwùjọ àti àṣà ṣùgbọ́n ní nǹkan bí Séńtúrì Ògún ni tíọ́rì náà búrẹkẹ̀ láwùjọ àwọn akadá ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí tíọ́rì yìí o ní tíọ́rì tí o tẹ̀lé ìlànà àti èrò yìí jẹ èyí tí o jẹmọ tíọ́rì sáyẹ́ńsì lórí àwùjọ ènìyàn Ohun tí ó sì jẹ àjólórí rẹ̀ ni akitiyan tí àtọkunrìn àtobìnrin ń ṣe láti jàjàgbara kúrò lọ́wọ́ àwọn arẹ́ nijẹ Ètò olókòwò aládàńlá fààyè gbà ìpínsẹ́sẹ́ ó sí fààyè gba ìmọ̀ èrò to lágbára Ètò okoòwò fẹjú sí Ó sì mú ìtẹ̀síwájú bá àwùjọ Ṣùgbọ́n nípa ètò ọrọ̀ajé yìí fààyè gba ìréjẹ àti ìkọlura agbára àwọn ti ó fẹ́ ṣèlú Nítorí àwọn to ba ṣèlú ló lágbára àti mójútó ètò ọrọ̀ajé nípa ìdí èyí èyí lòdì sí ìjọba a máa wá láti ọ̀dọ̀ àwọn tí à ń gàbalé lórí ìtaninù àti ká rẹ́nijẹ máa ń pọ̀ ní àwùjọ olókòòwò aládàńlá Gẹ́gẹ́ bí àlàyé Adéyẹmí nígbà tí o ń sọ̀rọ̀ lórí tíọ́rì tí o tẹ̀lé ìlànà àti èrò àlàyé pé Lítíréṣọ̀ jẹ́ asojú ẹgbẹ́ kan Láwùjọ ohun tí a ba ń kà nínú lítíréṣọ̀ èròǹgbà àwọn ẹgbẹ́ ti a ń gàba le lórí ní àwùjọ ohun èlò sí lọ jẹ fún àwọn aláṣẹ láti jẹ kí ipò wọn dúró sinsin kí o máa ba a sọnù lọ́wọ́ wọn Àwọn agbátẹrù tíọ́rì yìí pín sí ọnà méjì Àwọn ìsọ̀rí kìíní gbà pé ìbáṣepọ̀ to gbórìn wa láàárín iṣẹ́ lítíréṣọ̀ àti ètò ọrọ̀ajé tó ba wà lode ní yóò sọ irú lítíréṣọ̀ tí àwùjọ máa ní Ní ìdàkejì àwọn mìíràn bí i gbà pé atúnnirọ bí agogo ni lítíréṣọ̀ jẹ o sí lè yí ìpinnu àwọn èèyàn àwùjọ padà Àwọn ìsọ̀rí méjèèjì yìí ló gbà pé àjọsepò wà láàárín iṣẹ́ lítíréṣọ̀ àti èrò báyéṣerí Tíọ́rì yìí gbàgbọ́ pé iṣẹ́ tí lítíréṣọ̀ ń ṣe ni láti ṣe alukoro ètò báyéserí àwọn tí ó wà nípò alásẹ Adéyẹmí fí yéwà pé irú èrò báyéṣerí yìí le àwùjọ sẹ́yìn tàbí kí o sun síwájú o tilẹ̀ lè tako irú èrò tí o ba jẹ asọni dèrò ẹ̀yìn Irú àpẹẹrẹ yìí ní a rí nínú ìwé Bámidele Ẹlẹ́wà Sàpón tí Báyọ̀ Adébọ̀ kọ tí o fí ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tako èrò báyéṣerí àwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè yìí àti ètò olókòwò aládàńlá tí ó mú ọ̀rọ̀ àwọn aláṣẹ máa pọ̀ sí nítorí àwọn ló ń darí ètò ọrọ̀ajé orílẹ̀èdè Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lọ ṣe mú kí àwọn mẹ̀kúnnù máa kúrò lójú kan tí wọ́n sí ń rápálá nínú ìṣẹ́ àti ìyà Òǹkọ̀wé tako ètò ọrọ ajé olókòwò aládàńlá èyí tó o fi àyé gba ìrénijẹ àti ìkọlura agbára àwọn tó fẹ́ ṣèlú nítorí àwọn tó bá ń ṣèlú ló lágbára àti mójú to ètò ọrọ ajẹ́ Itaninu àti kárẹ̀nijẹ máa ń pọ ní àwùjọ ètò olókòwò aladanla Èyí ni o fa tí Bámídele fí jáde ilé ìwé pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí ti o yanranti ṣùgbọ́n nítorí pé kò ní alafẹ̀yìntì nídìí ọ̀rọ̀ ètò ìṣèlú àti ètò ọrọ̀ajé àwùjọ rẹ̀ ó di ẹní tí kò rí iṣẹ́ ní àwùjọ kan náà tí àwọn ọmọ alágbára ti ń rí iṣẹ́ láì ní ìwé ẹ̀rí to dáńtọ́ ORÍ KẸ́TA ÌTÚPALẸ̀ ÌWÉ ERÉONÍTÀN BÁMIDÉLÉ ẸLẸ́WÀ SÀPỌ́N ÌFÁÀRÀ Ní abala kẹ́ta yìí ni a ó ti ṣe àtúpalẹ̀ ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n a ó ṣe àgbéyẹ̀wò ìtàn ìgbésí ayé òǹkọ̀wé nítorí a gbàgbọ́ pé ìgbé ayé òǹkọ̀wé lè ní ipa lórí ìwé tó kọ Ó sì ṣe dandan kí a ṣe àkíyèsí èyí A ó wo àhunpọ̀ ìtàn ibùdó ìtàn ìfìwàwẹ̀dá àti bí wọ́n ti ṣe àfihàn ìṣẹ́ àti ìyà A ó ṣe àkíyèsí bí ìyà ṣe ń bá àwọn ẹ̀dá ìtàn fínra Nígbà tí àwùjọ tí ó bí ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n yóò kádìí abala yìí ÌTÀN ÌGBÉSÍAYÉ ÒǸKỌ̀WÉ Adébáyọ̀ Adébọ̀ ni orúkọ ẹni tí ó kọ ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n A bí Báyọ̀ Adébọ̀ ní ìlú Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kéje ọdún sí ìdílé onígbàgbọ́ Orúkọ bàbá rẹ̀ ni Adékúnlé Adébọ̀ nígbà tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Olúwafúnmiláyọ̀ Adébọ̀ Àgbẹ̀ paraku ni àwọn òbí rẹ̀ kí wọ́n tó fayé sílẹ̀ Adébáyọ̀ Adébọ̀ lọ sí iléìwé alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ ní Abẹ́òkúta ní ọdún sí ọdún ní ọdún yìí kan náà ni ó bẹ̀rẹ̀ iléìwé gírámà tí ó sì jáde níbẹ̀ ní olórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́kùnrin ìyẹn ni wọ́n fi jẹ nígbà náà Lẹ́yìn tí ó parí ilé ẹ̀kọ́ gírámà kò sí owó láti tẹ̀síwàjú èyí mú kí ó máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ káàkiri níbi tí ó bá ti rí iṣẹ́ Lára àwọn iṣẹ́ tí ó ṣe ni iṣẹ́ Lébìrà nílé iṣẹ́ àwọn tí wọ́n máa ń bá ènìyàn kọ ilé tí wọ́n ń pè ní ní ìlú Minna Lẹ́yìn tí ó kúrò nílùú Minna ni ó gba ìlú Àbújá lọ láti lọ máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó bá rí níbẹ̀ Bákan náà nígbà tí ó kúrò ní ìlú Àbújá ó gba ìlú Ìṣágámù lọ níbi tí ó ti lọ bá ènìyàn ta ohun èlò ìkọ́lé Lẹ́yìn tí ó kúrò níbi iṣẹ́ yìí ó tún lọ kọ́ iṣẹ́ tí a mọ̀ sí aránṣọ Tailor Ó kúrò ní ìlú Ṣágámù ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ọdún ó padà sí ìlú Abẹ́òkúta níbi tí ó ti ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ gbégilódò tí ó sí kúrò níbẹ̀ ní ọjọ́ kọ́kàndínlógún oṣù kejì ọdún Ọdún yìí náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ nílé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ kan tí a mọ̀ sí Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iléìwé yìí àwọn ìsín wẹẹrẹ ni ó ti bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n kí ó tó kúrò níbẹ̀ ní ọdún wọ́n fi jẹ ọ̀gá tí a mọ̀ sí Lẹ́yìn tí ó kúrò níléìwé yìí ó padà sí ìlú Ìbàdàn ó sì tún bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ayé rẹ̀ nípa ṣíṣe iṣẹ́ tí ó bá rí ní ṣíṣe Ó ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ní ìlú Ìbàdàn náà bí i iṣẹ́ asọ́nà kúkù lẹ́yìn tí ó padà sí ìlú Àbújá ó bẹ̀rẹ̀ sí ní bá ẹnìkan tí a mọ̀ sí Kọ́láwọlé Aderinokun ṣiṣẹ́ tí àwọn Òyìnbó ń pè ní ìyẹn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Lẹ́yìn tí ó kúrò lọ́dọ̀ Alàgbà Bankọla Aderinnokun ó padà sí ìlú Èkó níbi tí ó ti darapọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré eré orí ìtàgé tí a mọ̀ sí Ó bá wọn ṣe oríṣìíríṣìí eré bí Ẹyín Ọká Aawigbo Aya Òòṣà àti Ẹjọ́ Kẹ́jọ́ Nígbà tí ó di ọdún ni ó padà sí ìlú Ìbàdàn Ní ọdún yìí kan náà ni ó bẹ̀rẹ̀ iléìwé gíga ti ìlú Ìbàdàn ìyẹn Ìbàdàn tí ó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè lórí eré orí ìtàgé ìyẹn ó parí ní ọdún lára àwọn ìwé tí Báyọ̀ Adébọ̀ kọ nìwọ̀nyí i Lágídò ìwé ìtàn àròsọ ní ọdún ii Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n ìwé eréonítàn ní ọdún iii Ọmọ Oòduà ìwé ìtàn àròsọ Títí di òní ni ó sì ń kọ ìwé tà fúnra rẹ̀ ÀHUNPỌ̀ ÌTÀN NÍ ṢÓKÍ Ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú lẹ́tà tí Sẹ̀gilọlá àfẹ́sọ́nà Bámidélé kọ pé kí ó má bọ̀ wá sí ilé nígbà tí kò rí iṣẹ́ lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tí ó ti parí ilé ìwé Yunifásítì Bámidélé gbà láti padà sí ilé òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lásúnkànmí lẹ́yìn tí wọ́n ka lẹ́tà tí Sẹ̀gilọlá kọ̀ ọ́ Láṣúnkànmí gbà láti lọ sí Minna nígbà tí Bámidélé padà sí ìlú Abẹ́òkúta lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ Lẹ́yìn tí ó dé ìlú Abẹ́òkúta bàbá rẹ̀ gbà á níyànjú kí ó máa ṣiṣẹ́ àdáṣe kí ó máa nírètí wí pé ìjọba kan á fún un ní iṣẹ́ Ó gba ìmọ̀ràn bàbá rẹ̀ ó sì pinnu láti máa ta ẹ̀wà ṣíṣè ṣùgbọ́n látàrí wí pé kò sí owó tí a fi máa ta ẹ̀wà náà bàbá rẹ̀ mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Alàgbà olóyè Gẹ́gẹ́dẹ́ fún ìrànlọ́wọ́ owó tí yóò fi máa ṣiṣẹ́ àti owó tí yóò fi gba sọ́ọ̀bù Lẹ́yìn tí olóyè Gẹgẹdẹ fún un ní owó tán ni ó bẹ̀rẹ̀ òwò ẹ̀wà títà rẹ̀ ní pẹrẹu Kò pẹ́ sí àkókò yìí ó gba ìwé kan tí ó wá láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lásúnkànmí wí pé ó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó Òun àti ìyàwó àfẹ́sọ́nà rẹ̀ Sẹ̀gilọlá ni wọn jọ lọ sibi ìgbéyàwó náà Lẹ́yìn tí wọ́n padà dé sí ìlú Abẹ́òkúta ni Bámidélé bẹ̀rẹ̀ sí ní hùwà àìtọ́ sí ìyàwó àfẹ́sọ́nà rẹ̀ látàrí ìgbéyàwó alárinrin tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe Kò pẹ́ sí ìgbà náà ó padà ọ̀rẹ́ rẹ̀ Àkànjí tí ó mú un lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìyókù rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ adigunjalè tí olórí wọn ń jẹ Sílífá Ìrókò Ó darapọ̀ mọ́ àwọn adigunjalè yìí látàrí ìwà ọ̀kánjùwà ó gbàgbé ìyàwó àfẹ́sọ́nà rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé àwọn ọmọbìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ kiri Lẹ́yìn èyí ni ó ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Adétutù tí ayé gbọ́ tí ọ̀run sì mọ̀ pẹ̀lú Nígbà tí ó yá ó rò pé iṣẹ́ adigunjalè tí òun ṣe kò pé mọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ẹ̀yà ara àwọn ènìyàn èyí sì mú owó tó pọ̀ wálé fún un iṣẹ́ yìí ló ṣe títí tí ọwọ́ àwọn Ọlọ́pàá fi tẹ̀ ẹ́ tí wọ́n sì fi ẹ̀yìn rẹ̀ ti àgbá tí ó sì gba ibẹ̀ lọ sí ọ̀run alákeji ÀWÙJỌ TÓ BÍ ÌWÉ ERÉONÍTÀN BÁMIDÉLÉ ẸLẸ́WÀ SÀPỌ́N Láàárín ọdún sí ọdún tí a gba òmìnira ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà abẹ́ ìjọba Gẹ̀ẹ́sì ni Nàìjíríà wà ètò ọrọ̀ajé ìṣèlú àti ètò ìbáraẹnigbépọ̀ láwùjọ nígbà náà farajọ tí àwọn Òyìnbó Gẹ̀ẹ́sì Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún tí ìjọba orílẹ̀èdè kúrò lọ́wọ́ àwọn Òyìnbó Gẹ̀ẹ́sì tí ó di ti àwa ara wa Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni àyípadà ti dé bá bí i ètò ọrọ̀ajé ìṣèlú àti ètò ìbáraẹnigbépọ̀ láwùjọ oníkálùkù ti ní ẹ̀tọ́ láti ṣe nǹkan tí ó bá wù ú lásìkò tí ó bá fẹ́ Yàtọ̀ sí ayé àwọn Òyìnbó Gẹ̀ẹ́sì Láàárín ìgbà tí òǹkọ̀wé pé ọmọ ogún ọdún ìjọba orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti di tiwantiwa a ti rí àwọn onísòwò lóríṣìíríṣìí àwọn olóṣèlú oríṣìíríṣìí ẹgbẹ́ ni ó ti wà bí ẹgbẹ́ alákùkọ ẹgbẹ́ olówó ẹgbẹ́ ọlọ́pẹ ẹgbẹ́ oní ìgbálẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ gbogbo ẹgbẹ́ wọ̀nyí ní tiraka láti mú kí ẹgbẹ́ wọn gbòòrò si Bákan náà ni àwọn onísòwó kò gbẹ̀yìn bí a ti rí àwọn tí wọ́n ní obì ni a rí àwọn oníkòkó owó ti mú kí ayé lajú sí i ó ti fi ààyè sílẹ̀ fún oníkòkó láti kọ́lá ra ilẹ̀ mọ́tò rán ọmọ ní iléìwé gíga èyí tí kò wọ́pọ̀ ní ayé àtijọ́ Yàtọ̀ sí èyí àwọn Ọ̀mọ̀wé ń pọ̀ sí i ọmọ Yunifásítì ń pọ̀ si àìrí iṣẹ́ ń pọ̀ sí nítorí pé àwọn tí wọ́n wa iṣẹ́ pọ̀ ju iṣẹ́ tí ó wà nílẹ̀ lọ ètò ọrọ̀ajé ìlú yìí sì ń burú sí i Ní ọdún tí òǹkọ̀wé kọ ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n òṣèlú tí di bó o ba o pa bó ò ba o bù ú lẹ́sẹ̀ ó ti di tipá tìkúùkù o ti di iná ó ti di ti ẹni orí yọ ìpàdé dilé Àwọn ìwà olè jàǹdùkú ilé fífọ́ ìpànìyàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló gbòde kan nígbà náà ìfẹ́ owó ti wà lọ́kàn tọmọdé tàgbà olóṣèlú ń kówó lọ sí Òkè Òkun fún ìgbádùn òun àti àwọn mọ́lẹ́bí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí ní àwùjọ lónìí ọmọ olówó ò kàwé ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà mọ́ wọ́n ò kọ ilé tó dára sí ìlú wọn mọ́ òkè òkun ni wọ́n ń kówó orílẹ̀èdè Nàìjíríà lọ Èyí ni òǹkọ̀wé fi hàn nínú ìwé rẹ̀ nígbà tí Gómìnà ń kówó fún ọmọ rẹ̀ lọ sí Òkè Òkun Ó dára bí ó bá dé ìlú ọba lọ́hùnún sọ fún mama yín wí pé miliọọnu mẹ́wàá owó ló wà nínú báàgì yẹn Sọ fún un kí ó fi miliọọnù méjì méjì sí ilé ìfowópamọ́ lórúkọ ìwọ àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀oi Òǹkọ̀wé lo gbólóhùn wọ̀nyí láti jẹ́ kí a mọ bí àwùjọ ṣe rí ní àsìkò tí ó kọ ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n ó fi ìwà àwọn olóṣèlú hàn nígbà náà Bákan náà ni àwọn ọ̀dọ́ ń tiraka láti wá owó ní gbogbo ọ̀nà Ọmọ kékeré pínnísín mọ nǹkan tí à ń pè ní owó oyún inú àti àsẹ́ ìdí gbogbo wọn náà mọ ohun tí à ń pè ní owó Ayé ń polúkúrúmusu ọ̀gẹ̀dẹ̀ orílẹ̀èdè yìí ń bàjẹ́ a sọ pé ó ń pọ́n Ní ọdún ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ nígbà náà ni ó ṣokùnfà kíkọ ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Ní àsìkò yìí ayé ti yípadà ọmọ olówó ló ń rí iṣẹ́ ọmọ ẹni tí bàbá rẹ̀ mọ ènìyàn ló ń ríṣẹ́ olówó ló ń lówó lọ́wọ́ sí ní ojoojúmọ́ tí tálákà sì ń tiraka láti gòke láti rán ọmọ wọn lọ sí iléìwé wọn wá sọ ètò ìṣèlú orílẹ̀èdè Nàìjíríà di oyè ìdílé Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ nígbà náà farajọ èrò lórí tíọ́rì rẹ̀ tí ó ṣàlàyé pé; Àwọn tó bá ṣèlú lo lágbára àti mójú tó ètò ọrọ̀ajé nítorí ìdí èyí ìlòdí sí ìjọba a máa máyé láti ọ̀dọ̀ àwọn to ń gaba le lórí itaninu àti kárẹ́nijẹ máa ń pọ̀ ní àwùjọ olókoòwò aládàá ńláoi Àlàyé yìí farajọ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ ní àwùjọ nigbti òǹkọ̀wé kọ ìwé rẹ̀ ní àsìkò yìí ọmọ mẹ̀kúnnù kò ní àṣẹ láti ṣiṣẹ́ níbi tí ó bá wù ú nítorí bàbá rẹ̀ ò sí ní ipò wọn ò lè jẹ́ kí wọn mójú tó iṣẹ́ nítorí wọ́n ò ṣe òṣèlú Bákan náà ni àkókò yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí òbí wọn tiraka láti rán nílé ìwé ni wọ́n ò ríṣẹ́ ṣe láti fi bọ àwọn ẹbí wọn kí ìṣẹ́ àti ìyà lè dínkù Àpẹẹrẹ èyí ni a rí nínú ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n tí Bámidélé àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lásún parí ilé ẹ̀kọ́ gíga ọdún mẹ́rin gbáko ni wọ́n fi ń wa iṣẹ́ tí wọ́n kò ò rí Nígbà náà ìjọba orílẹ̀èdè Nàìjíríà ò mọ pébi ń pa ọmọ ẹnìkan ẹnu ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀ A rí ẹ̀rí èyí nínú lẹ́tà tí Sẹ̀gilọlá kọ sí Bámidélé Bámidélé máa fi àkókò rẹ sòfò ní wíwá iṣẹ́ kiri ìlú Èkó mọ́ Ìjọba àsìkò yìí kò náání ọjọ́ ọ̀la ará ìlú débi wí pé wọn yóò pèsè iṣẹ́ fún wọn oi Síwájú sí i ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà nígbà náà àwọn tíwọ́n lówó lọ́wọ́ o le dálé iṣẹ́ sílẹ̀ wọ́n ń bẹ̀rù olè gbájúẹ̀ gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí ní kówó lọ sí òkè òkun wọ́n ń lọ dálé iṣẹ́ sílẹ̀ níbẹ̀ Àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀èdè ò ríṣẹ́ gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí ní hùwà àìtọ́ kiri Èyí ni òǹkọ̀wé ń fi hàn nínú ìwé rẹ̀ ó fi àwùjọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà ṣe rí ní àkókò tí ó kọ ìwé náà A rí àpẹẹrẹ èyí nínú lẹ́tà tí Sẹ̀gilọlá kọ sí Bámidélé Àwọn ọlọ́rọ̀ láàárín ìlú tí a ó bá tún gbọ́kànlé kàkà kí wọ́n ó dá ilé iṣẹ́ sílẹ̀ níbi tí a ti le máa ṣiṣẹ́ kí a máa rí oúnjẹ jẹ ìbẹ̀rù kò jẹ́ kí wọn ó ṣe bẹ́ẹ̀ òkè òkun ni wọ́n ń dá iléiṣẹ́ ńlá ńlá sí kiri oi Òǹkọ̀wé fi ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà hàn ó sì lo ìlú Èkó àti Abẹ́òkúta gẹ́gẹ́ bí ibùdó ìtàn nítorí àwọn ìlú ńlá ńlá báwọ̀nyí ni àwọn tí ó ń parí iléìwé gíga tí fẹ́ ṣiṣẹ́ àti wí pé ibẹ̀ ni olóṣèlú pọ̀ sí jù Òǹkọ̀wé fi hàn nínú ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n pé gbogbo ìgbà ni àwọn ọ̀dọ́ ń tiraka láti lọ sí iléìwé bóyá á jẹ́ sàn níjọ́ kan ṣùgbọ́n kàkà kí ó sàn lára ìyá àjẹ́ wọn níṣe ni ó ń fi gbogbo ọmọ rẹ̀ bí obìnrin Ní àwùjọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà nígbà náà kò sí ìpíndọ́gba èrè ètò ọrọ̀ajé àwùjọ àwọn aláṣẹ àti olówó nìkan ló ń rí èrè àwùjọ pín mọ́wọ́ ẹnu tiwọn nìkan ni wọ́n mọ̀ wọn ò mọ bóyá ìyà ń jẹ ará ìlú A rí àpẹẹrẹ irú ìwà báyìí nínú ìwé náà nígbà tí Gómìnà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Àmọ̀pé ń sọ̀rọ̀; Ìyà ń jẹ́ mẹ̀kúnnù ara ń ni ará ìlú ìwọ ń kó owó ìlú lọ fi pamọ́ sókè òkun Ẹ̀gbọ́n mi ẹ máa sépè fún mi mọọ́n mo wà nípò lónìí mo tún le máa dé ibẹ̀ mọ́ títí tí mo máa fi fi ilẹ̀ ṣaṣọ bora ọjọ́ iwájú àwọn ọmọ mi àtàwọn ọmọ tiyin pàápàá le dájú ni oi Bákan náà ní àwùjọ nígbà náà ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí kò le ṣiṣẹ́ tí ó bá rí nítorí bí ìlú ṣe rí ni wọn bẹ̀rẹ̀ sí ní jalè kiri irú àwọn ènìyàn báyìí ni Sílífá Ìrókò Kọ̀ǹkọ̀sọ̀ Àtíòro àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ bákan náà ni ètò ọrọ̀ajé olókoòwò aládàńlá ti mú kí ẹnu àwọn ènìyàn fẹ̀ owó tọ́rọ́ kọ́bọ̀ kò ká wọn lẹ́nu mọ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní wá owó ní gbogbo ọ̀nà èyí ló sun ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ̀ débi ìwà tí kò tọ́ Irú nǹkan wọ̀nyí ló sun Bámidélé débi ìwà olè jíjà nígbà tí owó ẹ̀wà tí ó ń tà kò tó o mọ́ Ọ̀kánjúwà ń dàgbà ọgbọ́n ń tẹ̀síwàjú ni ọ̀rọ̀ orílẹ̀èdè Nàìjíríà jẹ́ Ojoojúmọ́ ni nǹkan ń yípadà tí nǹkan sì ń wọ́n sí i Ti ìjọba àti àwọn olórí wa kò bá tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi sàdá lórí ọ̀rọ̀ tí ìṣẹ́ àti ìyà àìríṣẹ́ ń dá kalẹ̀ àfàìmọ̀ kí gbogbo ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà má di adigunjalè tán kí á máa sì jí ara wa tà tán nítorí owó IBÙDÓ ÌTÀN ÀRÒSỌ GẸ́GẸ́ BÍ ORÍSUN ÌṢẸ́ ÀTI ÌYÀ Nínú ìwé ìtàn àròsọ Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n òǹkọ̀wé lo àwọn ìlú ńlá ńlá bí Èkó Abẹ́òkúta àti Minna gẹ́gẹ́ bí ibùdó ìtàn Èrò ọ̀pọ̀ ènìyàn ni pé kò yẹ kí ìṣẹ́ àti ìyà wọ́pọ̀ ní àwọn ìlú wọ̀nyí bí kò ṣe ní àwọn ìlú kéréje Èrò yìí farapẹ́ èrò Gómìnà ìpínlẹ̀ Enugu tẹ́lẹ̀ rí nígbà tí ó sọ̀rọ̀ ó ní; Ní ayé àtijọ́ wọ́n máa ń sọ wí pé àwọn ìlú ìgbèríko ni ìṣẹ́ àti ìyà tí máa ń wáyé látàrí àwọn nǹkan bí i àìní oúnjẹ tí ó dára omi tí kò dára àìní owó láti rán ọmọ lọ sí iléìwé Ó ní ṣùgbọ́n ní òde òní àwọn ìlú ńlá ńlá ni ìṣẹ́ àti ìyà pọ̀ sí jù Òǹkọ̀wé mọ̀ọ́nmọ̀ lo ìlú Abẹ́òkúta tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí ó tóbi ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí ibùdó ìtàn láti fi yéwa pé kò sí bí ènìyàn ṣe le wa ní àwọn ìlú wọ̀nyí tí kò ní nílò owó nítorí pé ohun gbogbo ni wọ́n máa ń fi owó ṣe Bẹ̀rẹ̀ láti orí ilé gbígbé owó ni wọ́n ń fi ń da ìdọ̀tí nù ní ọ̀pọ̀ ibòmíràn owó ni a sí ń fi wọ ọkọ̀ ní èyí tí kò sí ní àwọn ìlú kéèkèké Ìbéèrè tí òǹkọ̀wé ń bèèrè ni pé áwo ni a ti fẹ́ ṣe tí a ó gbé ní ìlú wọ̀nyí láì lówó lọ́wọ́? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ló mú Bámidélé di ẹni tí ó ń ta ẹ̀wà ṣíṣè láì ṣe obìnrin Òǹkọ̀wé lo àwọn ìlú ńlá ńlá gẹ́gẹ́ bí ibùdó ìtàn láti fi hàn pé àwọn tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá jà ní ìlú ńlá pọ̀ látàrí ìlú tí kò fara rọ Bámidélé tí ó jẹ́ olú ẹ̀dá ìtàn ṣe àgùnbánirọ̀ ní ìlú Èkó Ìlú Èkó jẹ́ ìlú ńlá tí ó tóbi púpọ̀ tí ọrọ̀ajé ibẹ̀ sì jí pépé ṣùgbọ́n síbẹ̀ àwọn tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra ní ìlú náà ní ó pọ̀ jùlọ nítorí pé púpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni kò fẹ́ dúró sí ìletò nítorí ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà fún wọn ní àwọn ìlú ńlá ńlá tí kò sí ní ìletò Fún ìdí èyí èrò pọ̀ ju iṣẹ́ tó wà nílẹ̀ lọ èyí ni Lásún jẹ́rìí sí nígbà tí ó ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ ó ní; A ń wá iṣẹ́ tí kò sí kiri ojoojúmọ́ ni a ń fi ẹsẹ̀ palẹ̀ kiri gbogbo òpópónà ìlú Èkó oi Gẹ́gẹ́ bí àbájáde kan lórí ẹ̀rọ ayélujára ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kejìlá ọdún sọ báyìí pé; Àìrí iṣẹ́ ló máa ń yí sí ìṣẹ́ àti ìyà Wọ́n gbàgbọ́ wí pé tí kò bá sí iṣẹ́ ìṣẹ́ àti ìyà a máa peléke sí i ní àwùjọ ni Nítorí ẹni tí kò rí iṣẹ́ kò le rí owó láti tọ́jú àwọn ẹbí àti ará Òǹkọ̀wé fi yéwa pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìṣẹ́ àti ìyà farahàn ní ìlú kéréje Síbẹ̀ kò pọ̀ tó àwọn ìlú ńláńlá nítorí ìdí èyí ni òǹkọ̀wé ṣe lo ìlú ńlá bí i Èkó Abẹ́òkúta àti Minna gẹ́gẹ́ bí ibùdó ìtàn Lára ibùdó ìtàn tí òǹkọ̀wé lò ni ìlú Abẹ́òkúta tí a bá ń dárúkọ àwọn ìlú tí wọn ní òkìkí ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà ni òní ìlú Abẹ́òkúta kò gbẹ̀yìn Òǹkọ̀wé wí pé bí olówó ṣe wà ni àwọn tálákà náà wà Lára àwọn olówó ni a ti rí Gómìnà olóyè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ bẹ́ẹ̀ sì ni a rí àwọn tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra ní inú ìlú náà lára wọn ni a ti rí Bámidélé bàbá Bámidélé Sẹ̀gilọlá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ní àkókò àti ìgbà tí Bámidélé dé ìlú Abẹ́òkúta kò sí èyíkéyìí nínú àwọn mọ̀lẹ́bí tí ó lówó láti ràn án lọ́wọ́ láti fi bẹ̀rẹ̀ òwò tí ó fẹ́ ṣe Èyí ló mú un dé ọ̀dọ̀ olóyè tí ó ràn án lọ́wọ́ fún owó tí ó fi bẹ̀rẹ̀ ẹ̀wà títà rẹ̀ òǹkọ̀wé fẹ́ kí a mọ̀ wí pé kò sí ìlú tí ìṣẹ́ àti ìyà kò sí pàápàá àwọn ìlú ńlá ńlá nítorí bùkátà oníkálùkù ló tí tó ó gbé Òǹkọ̀wé lo ìlú Abẹ́òkúta gẹ́gẹ́ bí ibùdó ìtàn ó fẹ́ kí ó yé àwùjọ pé bí o ti wù kí ìlú náà tóbi tó ìṣẹ́ àti ìyà máa ń bá àwọn kan fínra Síwájú sí ìṣẹ́ àti ìyà tí ó wà ní ìlú ńlá ló mú kí géńdé Ọlọ́run máa ta ẹ̀wà ṣíṣè nítorí dandan ni kí a jẹun dandan ni kí a san owó ilé èyí ni ó mú kí bàbá Bámidélé gba ọmọ rẹ̀ nímọ̀ràn pé; Àtẹ́lẹwọ́ ẹni kì í tan ni jẹ ìdí rẹ̀ rè é tí mo ṣe fimú fínlẹ̀ káàkiri ìlú wa láti ṣe ìwádìí irúfẹ́ iṣẹ́ tí o lè dáwọ́ lé Mo wá rí i wí pé àwọn tí wọ́n ń ṣe ẹ̀wà tà nílùú Ẹ̀gbá níbi ò tó nǹkan oi Òǹkọ̀wé fi yé wa pé àìsí iṣẹ́ ló ṣokùnfà ìṣẹ́ àti ìyà Ìṣẹ́ àti ìyà ló sì bí ìwà ọ̀daràn tó peléke sí àwùjọ wa Àwọn tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra ń wá gbogbo ọ̀nà láti mú kí ara tu wọ́n ì bá a ṣe nípasẹ̀ olè jíjà Òǹkọ̀wé fi èyí hàn nígbà tí Bámidélé darapọ̀ pẹ̀lú àwọn Sílífá Ìrókò Ẹlẹ́wà Sàpọ́n ṣe o rí àwa tí ó ń wò yìí a ò lówó kan bí alárà tí a ń ṣe Gbajúmọ̀ ni iṣẹ́ tiwa Ìgárá ni wá Èmi olóyè Sílífá Ìrókò sì ni Ààrẹ apàṣẹ wa iṣẹ́ náà ẹnu ya Bámidélé ó yanu kò lepa á dé mọ́ Oi Bákan náà ìṣẹ́ àti ìyà ló mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n fi darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìgárá ọlọ́ṣà máà le kúrò níbẹ̀ mọ́ nítorí owó tí wọn ń rí ti fẹjú mọ́ wọn Bákan náà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ò ní àǹfààní láti jáde mọ́ nítorí wọ́n ti mulẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó kù ìdí nìyí tí ìwà ìbàjẹ́ ṣe ń pọ̀ sí ní àwùjọ Òǹkọ̀wé fi bí wọ́n ṣe máa ń ṣe hàn nígbà tí wọn ń bá Bámidélé sọ̀rọ̀; Ẹlẹ́wà Sàpọ́n ó ti wá mọ àṣírí iṣẹ́ wa báyìí o o ò gbọdọ̀ sọ wí pé o ò ṣe mọ́ Ń ò ṣe mọ́ ò sí loro tiwa o Bí ó bá gbìyànjú rẹ̀ pẹnrẹn a jẹ́ wí pé ó ti múra àtipadà sájùlé ọ̀run oi Bákan náà ni òǹkọ̀wé lo ìlú Minna gẹ́gẹ́ bí ibùdó ìtàn Òǹkọ̀wé lo ibùdó ìtàn yìí láti jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún wa pé àwùjọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà tí a wà yìí pín sí ọ̀nà méjì a ní àwọn olówó tí wọ́n ń darí ètò ọrọ̀ajé ètò ìṣèlú a sì ní àwọn kòlàkòsagbe ènìyàn àwọn olówó ní agbára láti ṣe ohun tó bá wù wọ́n nítorí ọwọ́ wọn ni àṣẹ orílẹ̀èdè wa Ohunkóhun tí wọ́n ba ṣe ma ń jọ àwọn mẹ̀kúnnù lójú tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé èyíkéyìí nínú wọn tí kò bá ní ìpinnu ọkàn láti máà hù ìwà ìbàjẹ́ máa ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà ìbàjẹ́ bí i; ìjínigbé oògùn owó ṣíṣe olè jíjà alari àti le bá àwọn olówó dọ́gba Àpẹẹrẹ èyí la rí ní ìlú Minna tí Bámidélé tìtorí wí pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ fẹ́ ọmọ olówó tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní si ìwà hù Ní ìgúnlẹ̀ òǹkọ̀wé fi yé wa wí pé ìṣẹ́ àti ìyà ní àwùjọ ní òde òní kì í ṣe fún ìran tàbí ìdílé kan ó ti di nǹkan tí ó ń bá gbogbo ènìyàn fínra Òǹkọ̀wé tún ṣàlàyé wí pé ìṣẹ́ àti ìyà kì í ṣe fún ìlú kéréje nìkan ó wọ́pọ̀ ní àwọn ìlú ńlá ńlá náà torí ìdí èyí ni òǹkọ̀wé fi lo àwọn ibùdó ìtàn bí i Èkó Abẹ́òkúta àti Minna láti jẹ́ kí a mọ̀ wí pé àwọn ìlú wọ̀nyí ganan ni ìṣẹ́ àti ìyà pọ̀ sí jù Òǹkọ̀wé fi yé wa pé àìrìnjìnnà láì rábuké ọ̀kẹ́rẹ́ ni ọ̀rọ̀ ìṣẹ́ àti ìyà jẹ́ láwùjọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà kò sí ìlú tí kò sí ibi gbogbo ni ìṣẹ́ àti ìyà ti ń bá àwọn ènìyàn fínra ÌFÌWÀWẸ̀DÁ GẸ́GẸ́ BÍ ÀFIHÀN ÌṢẸ́ ÀTI ÌYÀ Ìfìwàwẹ̀dá túmọ̀ sí ọgbọ́n tàbí ète tí òǹkọ̀wé lò láti fi àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ hàn ọ̀nà tí òǹkọ̀wé gbà gbé ìwà wọ àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ lọ́nà láti jẹ́ kí ìtàn náà jọ ìṣẹ̀lẹ̀ ojú ayé Oríṣìíríṣìí ni àwọn ẹ̀dá ìtàn tí òǹkọ̀wé lò nínú ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Àwọn ẹ̀dá ìtàn wọ̀nyí pín sí ọ̀nà mẹ́ta; òpómúléró ẹ̀dá ìtàn amútàn tẹ̀síwàjú tàbí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀dá ìtàn nígbà tí oríṣìí ẹ̀dá ìtàn kẹ́ta jẹ́ sárépẹgbẹ́ ẹ̀dá ìtàn Òǹkọ̀wé máa ń gbé ìwà wọ àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ láti mú kí ìtàn rẹ̀ jọ ìṣẹ̀lẹ̀ ojú ayé èrò tàbí ìṣe tí òǹkọ̀wé bá fẹ́ rán sí àwùjọ máa ń wáyé tàbí di mímọ̀ nípa ipa tí ẹ̀dá ìtàn kó Bí àpẹẹrẹ òǹkọ̀wé tí ó fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn àgbẹ̀ ṣe ń lọ sí oko tí ó wa lo ẹ̀dá ìtàn tí ìṣeṣí àti ìhùwàsí rẹ̀ jọ ti alákọ̀wé a o rí i wí pé èyí kò ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìwé náà Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ sáájú wí pé oríṣìí ẹ̀dá ìtàn mẹ́ta ni ó wà Ẹni tí ó jẹ́ òpómúléró nínú ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n ni Bámidélé nígbà tí àwọn amútàn tẹ̀síwàjú jẹ́ àwọn ẹ̀dá ìtàn bí i Sẹ̀gilọlá Àkànjí olóyè Sílífá Ìrókò bàbá Bámidélé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Bákan náà ni a rí àwọn sárépẹgbẹ́ ẹ̀dá ìtàn àwọn ẹ̀dá ìtàn tí ó jẹ́ wí pé tí wọ́n kò bá sí nínú ìtàn kò ba ìtàn jẹ́ Lára wọn ni Bọ́láńlé Ní báyìí a ó ṣàlàyé ẹ̀dá ìtàn bí wọ́n ṣe fi ìṣẹ́ àti ìyà hàn nínú ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n BÁMIDÉLÉ Bámidélé ni olú ẹ̀dá ìtàn tí ìtàn yìí rọ̀ mọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin Ó wá láti ìdílé mẹ̀kúnnù tí ìṣẹ́ àti ìyà ti bá wọn mulẹ̀ ìdílé tí wọ́n tiraka láti rán ọmọ lọ sí iléìwé ìdílé tí ó nira fún wọn láti jẹun ìdílé tí wọn kò rówó rán ọmọ wọn lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ A rí èyí nígbà tí bàbá Bámidélé lọ bá olóyè fún ìrànlọ́wọ́ owó Owó tí yóò fi bẹ̀rẹ̀ òwò ọ̀hún ló wá kù báyìí yóò sì tún gba sọ́ọ̀bù oi Iṣẹ́ ẹ̀wà títà lásán ni Bámidélé fẹ́ ṣe tí kò sí owó tí àwọn òbí rẹ̀ le kó fún un láti fi bẹ̀rẹ̀ àfi tí wọ́n bá tún lọ tọrọ owó Baidele ni òǹkọ̀wé fi orí ìwé rẹ̀ sọ òǹkọ̀wé fi hàn bí ìṣẹ́ àti ìyà ṣe ń bá a fínra tó dé bi wí pé ẹ̀wà ṣíṣè tà ló kù ku ọkùnrin kùrìn Bámidélé tí ó jẹ́ olú ẹ̀dá ìtàn wá láti ìdílé tí ó jẹ́ wí pé kò sí ẹnìkan tí ó lówó lọ́wọ́ níbẹ̀ Ìdílé tí wọ́n kò fí ojú ara wọn rí nǹkan ayọ̀ tí wọ́n á náwó nára Èyí ló jẹ́ kí ìgbéyàwó ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lásún jọ ọ́ lójú nígbà tí ó rí bí wọ́n ṣe náwó nára níbi ìgbéyàwó náà A rí èyí nígbà tí ó ń ronú lẹ́yìn tí wọ́n kúrò níbi ìgbéyàwó ọ̀rẹ́ rẹ̀ Un ó ga o Lásún ló ṣe ìgbéyàwó tó lárinrin báyìí à bí ẹ wo àwọn èèyàn jàkànjàkàn Àwọn lóokọ lóokọ káàkiri orílẹ̀èdè yìí tí wọ́n péjú pésẹ̀ síbi ìgbéyàwó rẹ̀ oi Ìṣẹ́ àti ìyà tí ó ti bá àwọn Bámidélé mulẹ̀ ní ìdílé wọn ló jẹ́ kí ìgbéyàwó Lásún ọ̀rẹ́ rẹ̀ jọ ọ́ lójú débi wí pé ọ̀nàkọnà ló bẹ̀rẹ̀ sí wá owó òun náà fẹ́ ṣe ìgbéyàwó tó dùn bí i ti ọ̀rẹ́ rẹ̀ èyí ló mú un pàdé ọ̀rẹ́ rẹ̀ Àkànjí tí ó ń ṣe agbódegbà fún àwọn adigunjalè nítorí ìṣẹ́ àti ìyà tí o ń bá àwọn náà fínra Iṣẹ́ àti ìyà lọ sún Bámidélé débí ìwà tí o hun nítorí o fẹ́ ni owó lọ́wọ́ lọ́na kọ̀na iṣẹ́ ẹwà tí o ń ta kò ká a mo A rí èyí nígbà tí Bámidélé àti Àkànjí pàdé ara wọ́n Bámidélé Eẹ a sa jẹ ń jẹnu àìrí kan ṣe kan náà lọ sun mi de ìdí èyí Àkànjí O dára Bí mọ ba fi ọ̀nà ọ̀wọ̀ mìíràn tí o ni owó lórí ju èyí ló hàn ẹ ǹjẹ́ oo le ṣe Bámidélé Taile ṣe e ti jẹ? Bówó ba tí wà lórí rẹ daradara Ń o se Oi Òǹkọ̀wé fi hàn wa pé iṣẹ́ àti ìyà lo sun un Bámidélé débi iṣẹ́ kí í ṣe òhun ló mú un ṣe iṣẹ́ tí ó bá rí tí owó sí wa níbẹ̀ Òǹkọ̀wé lo ẹ̀dá ìtàn yìí láti ṣe àfihàn ọsẹ́ tí ìṣẹ́ àti ìyà ni lórí àwọn ènìyàn àwùjọ Bákan náà ni òǹkọ̀wé fẹ kí a mọ̀ wí pé bí iṣẹ́ àti ìyà ba pọ ju tí ènìyàn wa jàjà rí ọ̀nà àbáyọ bí agogo ni orí ẹni náà á máa ṣiṣẹ́ Èyí lári nígbà tí Bámidélé tí n rówó nínú iṣẹ́ adigunjalè o tún wa tẹ̀síwájú o bẹ̀rẹ̀ síní ta ẹ̀yà ara ènìyàn ní èyí tí o lówó lórí ju adigunjalè lọ A rí èyí nígbà tí wọn Pa Mayọmi ọmọ olóyè Orí Máyọmi wà ní ọwọ́ Àtíòro kọ̀ǹkọ̀sò ìrú àpò saka tí o ń kan fún ẹjẹ nínú àpò yìí ni won kò ẹ̀yà ara Máyọ̀wá tí wọn tí kun sí wẹ́wẹ́ oi BÀBÁ BÁMIDÉLÉ Ẹ̀dá ìtàn mìíràn ní Bàbá Bámidélé gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra Òǹkọ̀wé fi Bàbá Bámidélé hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra ṣùgbọ́n síbẹ̀ òǹkọ̀wé fẹ́ kí a mọ wí pé tí ìṣẹ́ àti ìyà bá pọ jú ó máa ń fún ènìyàn láǹfàaní láti ronú lórí nǹkan tí a ṣe tí a mu owó wọlé Òǹkọ̀wé fi Bàbá Bámidélé hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ni ìrònú bí o tile jẹ́ pé ìṣẹ́ àti ìyà náà pọ̀ tí o le gba ọmọ rẹ̀ ni ìrònú Bákan náà ni òǹkọ̀wé fi hàn pé bí iṣẹ́ àti ìyà náà ṣe fọ̀ tó ní o mu kí Bàbá Bámidélé gba ọkùnrin kùmìn ní ìmọ̀ràn kí o máa ta ẹwà ṣíṣe A rí èyí nígbà tí Bàbá Bámidélé ń ba Bámidélé sọ̀rọ̀ Ọmọ mi mo jókòó mo ronú mo ro o wí pé bí ijọbá bá kọ̀ tí wọn o náání ará ìlú tí wọn kọ̀ tí wọn o fún ọ níṣẹ́ bíwọ náà bá lè wá iṣẹ́ kan dáwọ́ le lórí funra rẹ ìdí rẹ̀ ree tí mọ se fimú fínlẹ̀ káàkiri ìlú wa láti se ìwádìí irúfẹ́ iṣẹ́ tí o le dáwọ́ le mo wa rí i wí pé tà nílùú Ẹ̀gbá níbi wọn ò to nǹkan oi ÀKÀNJÍ Ẹ̀dá ìtàn mìíràn tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra ní Àkànjí Òǹkọ̀wé lo Àkànjí láti bu ẹnu tẹ̀ lu àwọn adájọ́ ní àwùjọ Òǹkọ̀wé fi hàn pé ìṣẹ́ àti ìyà tí o ń bá Àkànjí fínra ló jẹ́ kí o máa lè sọ òtítọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ iṣẹ́ tí àwọn Sílifá Ìrókò ń ṣe síbẹ̀ nítorí àtije àtimu kò tú àṣírí wọn Gẹ́gẹ́ bí a sí tí mọ iṣẹ́ àwọn adájọ́ wí pé wọ́n máa tú àṣírí ìwà ìbàjẹ́ tí o ń lọ ni àwùjọ ni ṣùgbọ́n síbẹ̀ tórí ìṣẹ́ àti ìyà tí o ń bá Àkànjí fúnra kò le tu àṣírí àwọn Sílifá nítorí àwọn lọ ń fún ní oúnjẹ A rí àpẹẹrẹ èyí nígbà tí Àkànjí ń ba Bámidélé sọ̀rọ̀ Emí ni lọ́yà wọn bí mo ba sí ni kí wọn fi ọ̀nà owó wọn hàn ọ́ o da mi lójú wí pé wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ láàárín ose díẹ̀ ìwọ náà sí rí ìyípadà oi Òǹkọ̀wé fí Àkànjí hàn gẹ́gẹ́ bí adájọ́ tí o tìtorí owó darapọ̀ mọ́ àwọn adigunjalè tí o wa di abenugan nínú ìwà burúkú OLÓYÈ SÍLIFÁ ÌRÓKÒ Ẹ̀dá ìtàn mìíràn ni Sílifá Ìrókò gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà fún àwọn adigunjalè Ìṣẹ́ àti ìyà ló sún obìnrin débi ìsẹ́ olè jíjà débi wí pé òun tún ni ìyá ìsàlẹ̀ àwọn olè Òǹkọ̀wé fẹ́ kí a mọ̀ wí pé kò sí nǹkan tí ìṣẹ́ àti ìyà kò le sọ ènìyàn da Ìṣẹ́ àti ìyà ló sọ obìnrin di adigunjalè bí o tílẹ̀ jẹ wí pé kò yẹ kí a máa rí obìnrin nínú irú iṣẹ́ báyìí ṣùgbọ́n torí àtijẹ àtimu ó sọ obìnrin bìnrìn di adigunjalè Ààrẹ apàṣẹ wà á nínú ìwà ọ̀daràn A rí èyí nígbà tí ó ń bá Bámidélé sọ̀rọ̀ Gbájùmọ ní isẹ́ tiwa ìgárá ní á Emí olóyè Sílifá Ìrókò sí ni Ààrẹ apàṣẹ wà á ìṣẹ́ náà oi GÓMÌNÀ Ẹ̀dá ìtàn mìíràn tí òǹkọ̀wé ṣe àfihàn nínú ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n ní Gómìnà òǹkọ̀wé fi yé wa wí pé ika o dọ́gba bí a ṣe rí olówó náà ní a rí mẹ̀kúnnù Lára àwọn olówó ní Gómìnà tí o ní àsẹ láti ṣe nǹkan tí o ba fẹ́ lásìkò tí o ba fẹ tí kò sí ẹni tí a bì i leere Àwọn ni ijọbá wa lọ́wọ́ wọn àwọn ni wọn ń sí owo ìlú bí o ṣe wu wọ́n Wọ́n o máa ń kò owó ìlú lọ sí òkè òkun fún ìgbádùn ara wọn àti àwọn ẹbí wọn A rí èyí nígbà tí Gómìnà ń bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ Ó ní O dára bí o bá de ìlú ọba lohunun sọ fún mama yìí wí pé miliọọnu mẹwa owó lọ wà nínú baagi yẹn Sọ fúnun kí o ti miliọọnu Méjì méjì sí ilé ìfowópamọ́ lórúkọ ìwọ́ àti ẹgbọ́n rẹ̀ Àbọ́rò mi o yẹ ẹ ọ̀ oi ADÉTUTÙ Ẹ̀dá ìtàn mìíràn tí òǹkọ̀wé lò ni Adétutù gẹ́gẹ́ bí ìyàwó Bámidélé Òǹkọ̀wé lọ Adétutù láti fi ọsẹ́ tí ìṣẹ́ àti ìyà ń da kalẹ̀ ní àwùjọ pàápàá láàárín àwọn obìnrin Òǹkọ̀wé fi yé wa pé ìṣẹ́ àti ìyà tí sọ ọmọbìnrin di nǹkan mìíràn Ó tí sọ wọ́n di onírìnkúrìn Irú èyí la rí nígbà tí Bámidélé padà Tutù owó tí o rí lọ́wọ́ Bámidélé kò jẹ́ kí o béèrè iṣẹ́ tí ó ń ṣe lọ́wọ́ rẹ owó tí fẹjú mọ́ ọn ìfẹ́ owó tí jọba lọ́kàn rẹ Kò jẹ́ kí o ro ọ̀rọ̀ Bámidélé lemeeji tí o fi gbà sí lẹ́nu A rí èyí nígbà tí Bámidélé ń ba ọ̀rẹ̀ Tutù sọ̀rọ̀ Bámidélé Ọmọbankẹ Àlàkẹ́ ṣe waa gba mí laaye láti ba Tutù ni gbólóhùn fún ìsẹ́jú díẹ̀ Bankẹ Pẹ̀lú gbogbo ọ̀kan mi mo yonda ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ Àwọn ẹ̀dá ìtàn mìíràn tí òǹkọ̀wé tún lọ ni àwọn ọlọ́pàá Òǹkọ̀wé fi àwọn ọlọ́pàá hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o ṣe fọkàn tan Nítorí bí ìṣẹ́ àti ìyà ṣe pọ̀ tó ní àwùjọ síbẹ̀ wọn ó gbowó ẹ̀yìn láti lè máa lè tú àṣírí àwọn tí o ń hùwà ìbàjẹ́ síta Òǹkọ̀wé fẹ́ kí a mọ̀ wí pé àwọn olè yìí le fún àwọn ọlọ́pàá lówó gọbọbi láti le bò wọ́n ní àṣírí ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́pàá kò gba owó ẹ̀yìn wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan tí ijọbá ń ṣe fún wọn ṢẸ̀GILỌ́LÁ Ẹ̀dá ìtàn mìíràn ni Ṣẹ̀gilọ́lá òǹkọ̀wé lo Ṣẹ̀gilọ́lá gẹ́gẹ́ bí ìyàwó Bámidélé Òǹkọ̀wé lo Ṣẹ̀gilọ́lá láti jẹ kí a mọ̀ wí pé kò sí bí ìṣẹ́ àti ìyà ṣe le máa bá tọkùnrin tobìnrin fínra tí ìfẹ́ bá wa láàárín wọn wọn a máa fẹ́ràn ara wọn sí ni òǹkọ̀wé fi Ṣẹ̀gilọ́lá hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra ṣùgbọ́n síbẹ̀ ìfẹ́ Bámidélé wà lọ́kàn rẹ̀ Bí o tile jẹ wí pé Bámidélé ó ní nǹkan kan síbẹ̀ ó nìfẹ́ rẹ̀ ẹ̀ Èyí la rí nígbà tí Bámidélé ń ba a sọ̀rọ̀ Èmi rórun tó burú nínú kí o máa se ẹwà tà o àti wí pé ẹni tí ó ṣe bí aláàárù lóyìngbò oi Yàtọ̀ fún wíwọ orúkọ ẹ̀dá ìtàn òǹkọ̀wé tún fún àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ lorúkọ nípa isẹ́ tí wọ́n ń se Ní àwùjọ Yorùbá àwọn adigunjalè kì í sábà jẹ orúkọ tí a mọ wọn mọ wọ́n máa ń jẹ orúkọ àlàje lára àwọn orúkọ wọ̀nyí ni Àtíòro Kọ̀ǹkọ̀sọ̀ ìgbín ÀTÍÒRO Tí a bá wo orúkọ tí òǹkọ̀wé fún ẹ̀dá ìtàn yìí a máa rí wí pé o ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ìwà rẹ̀ Ẹyẹ kan ló ń jẹ Àtíòro tí ẹnu rẹ̀ kì í dilẹ̀ nígbà kankan Irú ìwà yìí la rí nínú ìwà Àtíòro Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé ó wà nínú ìṣòro ẹnu rẹ̀ kò tún dilẹ̀ A rí èyí nígbà tí o ń wa ní àgọ́ ọlọ́pàá pẹ̀lú Kọ̀ǹkọ̀sọ̀ Kọ̀ǹkọ̀sọ̀ Ojúmọ́ mọ A o gbọ poroporo odó Ògànjọ́ ló gun gàn yìí oi KỌ̀ǸKỌ̀SỌ̀ Gẹ́gẹ́ bí a tí mọ wí pé nǹkan tí a da tàbí ohun èlò tí a fi ń jọ èlùbọ́ gaari ògi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní Kọ̀ǹkọ̀sọ̀ Jíjò ní o máa ń jò ká gbogbo ara Kọ̀ǹkọ̀sọ̀ nínú ìwé náà kí dákẹ́ àfi kí ó máa sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo ẹnu rẹ̀ kì í mọ ẹnu Bí o ti rí wí pé ìyà ti ń jẹ òun lọ ti fẹ ka bòròbòrò Kàkà kí awa nìkan o dákú máa kuku jẹ́wọ́ Haa! Máa jẹ́wọ́ o oi Yàtọ̀ fún orúkọ tí òǹkọ̀wé fún àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ ìṣẹ́ àti ìyà ló sun wọn debé isẹ tí wọn ń ṣe débi wí pé wọ́n ò mọ nǹkan tí o tọ sí wọn ohunkoun tí ọ̀gá wọn ba tí fún wọ́n ló wọn lọ́rùnkìkì kí wọn ẹ̀tọ́ wọn Ní ìgúnlẹ̀ a rí i wí pé gẹ́gẹ́ bí àkorí iṣẹ́ yìí tí a pé ní ìṣẹ́ àti ìyà nínú ìwé eré onítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Òǹkọ̀wé lo ẹ̀dá ìtàn ibùdó ìtàn àwùjọ láti sàfihàn ìṣẹ́ àti ìyà Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé kò sí bí ẹ̀dá ìtàn tí òǹkọ̀wé máa lo kò ṣe ni ba kókó tí ó fẹ́ jẹ́ kí àwùjọ mọ mu ìdí nìyí tí òǹkọ̀wé ṣe fí àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ hàn Bákan náà ní ibùdó ìtàn àti àwùjọ tí òǹkọ̀wé ń tọka sí jẹ́ èyí tí ìṣẹ́ àti ìyà wọ́pọ̀ sí Àwùjọ to jẹ pé mekunun kò lẹ́nu ọrọ àwùjọ tí àwọn olórí kò ti bìkítà bí ọmọ ènìyàn jẹnu tàbí kí o jẹun kìkì kí ẹbí tiwọn sa tí yo ló kàn wọn Àwùjọ tí ìṣẹ́ àti ìyà tí sàkóbá fún lọ̀pọ̀lọpọ̀ Akẹ́kọ̀ọ́ jáde kò ríṣé iye wọ́n pọ̀ débi pé wọ́n da adigunjalè àwọn tí kò digunjalè rí ṣiṣẹ́ oníṣẹ́ bí i ti Bámidélé tó jẹ́ ọkùnrin tó ń ṣe ẹwà tà Àwùjọ tí ó jẹ́ wàhálà fún òbí láti tọ́ ọmọ Yorùbá bọ wọ́n ní bí òkété bá dàgbà tan ọmú ọmọ rẹ̀ ní í mu Ọmú Bámidélé kò tólẹ̀ lọ́mọ rárá débi tí ìyá àti bàbá rẹ̀ yóò máa muun Èyí ló mú kí òǹkọ̀wé máa béèrè fún ọ̀nà àbáyọ kí ìwà bururu le dópin kí àwọn ènìyàn àwùjọ wa lè fi ẹ̀dọ̀ lórí òróòro ORÍ KẸ́RIN ÌTẸ̀SÍWÁJÚ ÌTÚPALẸ̀ ÌWÉ ERÉ ONÍTÀN BÁMIDÉLÉ ẸLẸ́WÀ SÀPỌ́N ÌFÁÀRÀ Ní abala kẹ́rin yìí ní àti máa tẹ̀síwájú nípa ṣíṣe àtúpalẹ̀ ìwé eré onítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n A wó kókó inú ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú ìṣẹ́ àti ìyà Bákan náà ní a wo ọ̀nà tí èdè òǹkọ̀wé fi sí ẹnu àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ ṣe fi ìṣẹ́ àti ìyà hàn Yàtọ̀ fún èyí a wo ọgbọ́n tí òǹkọ̀wé lò láti fi ṣe àfihàn ìṣẹ́ àti ìyà láwùjọ Nígbà tí ìhà tí òǹkọ̀wé fúnra rẹ kọ sí ìṣẹ́ àti ìyà kò gbẹ́yìn nínú ohun tí à ó gbéyẹ̀wò KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ GẸ́GẸ́ BÍ ÀFIHÀN ÌṢẸ́ ÀTI ÌYÀ Ìwé eré onítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n kò wà fún àtipa ènìyàn lẹ́rinín lásán tàbí àti dá wa lára yá nìkan ó ní kókó kan gbógì tí òǹkọ̀wé fẹ fàyọ Ó ní ẹ̀kọ́ tí òǹkọ̀wé fẹ́ kí àwọn òǹkàwé oó ó lè jẹ mọ́ ètò ìṣèlú ètò ọrọ̀ajé ẹ̀sìn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ ní òǹkọ̀wé fẹ́ kí a kọ́ nínú ìwé eré onítàn rẹ ní èyí tí o jẹ kókó tí onkwe fẹ́ kí a fà yọ Gbogbo kókó náà ní a máa wò pẹ̀lú akori iṣẹ́ yìí ìṣẹ́ àti ìyà ní àwùjọ Lára àwọn kókó tí ó wà ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n ní ọsẹ́ tí àwọn olóṣèlú ń ṣe ní àwùjọ ìwà àwọn olóṣèlú ìwà ọ̀daràn ìfẹ́ ojúkòkòrò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ọ̀kan lára kókó èrò inú ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n ní ÒṢÈLÚ Àwọn adarí ijọbá olóṣèlú tí à ń lò lọ́wọ́ kò kọbiara sí ètò tí ó lè mú ayé dẹrùn fún mùtú mùwà Lára rẹ̀ ni àìrisẹ́ ṣe pàápàá àwọn tí wọ́n pari ilé ẹ̀kọ́ lọkùnrin àti lóbìnrin Èyí ló bí ìwà ìbajẹ́ bí i; adigunjalè ìpànìyàn fífi ọmọ àyà ìwà sẹ́só àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Òǹkọ̀wé lo Bámidélé láti jẹ kí a mọ ìyà tí o ń jẹ́ àwọn ọ̀dọ́ látàrí olórí tí kò dára tí a ni ní àwùjọ lónìí òǹkọ̀wé fi àwọn olórí wà hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó tí yó tí kọ mọ pé ebi ń pa mẹ̀kúnùn rárá ara wọn nìkan ní wọ́n mọ òǹkọ̀wé ṣe àfihàn nǹkan tí o ń lọ láwùjọ láti ọwọ́ àwọn olóṣèlú A rí Bámidélé gẹ́gẹ́ bí olú ẹ̀dá ìtàn tí o parí ilé ìwé iṣẹ́ ọdún mẹ́rin gbáko ni ó fi wá iṣẹ́ ti kò rí látàrí àwọn olórí tí kò dára tí wọn kò kún ojú òṣùwọ̀n to A rí èyí nínú lẹtà tí Sègilọla kọ sí Bámidélé ó ní Bámidélé máa fi àkókò rẹ sòfò ni wíwá iṣẹ́ ti kò sí kiri ìlú Èkó Ijọbá àsìkò yìí kò náání ọjọ́ ọlá ará ìlú débi wí pé wọn yóò pésè iṣẹ́ fún wọn oi Ní àwùjọ lónìí àìríṣẹ́ jẹ ọ̀kan lára okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ tí wọ́n parí ilé ìwé ni wọn ò rí iṣẹ́ láti fi tọ́jú ẹ́bí àti ara Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ òde òní ní wọ́n jẹ́ ìrètí àwọn òbí wọn Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí inú iṣẹ́ àti ìyà ní wọn tí tiraka láti rán ọmọ lọ sí ilé ni ìrètí wí pé tí ó ba de kì í o wa gbọn ìṣẹ́ àti ìyà yìí daarun ṣùgbọ́n látàrí irú ijọbá tí a ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn o rí iṣẹ́ ṣe láti fi bọ èbí àti ará kí ìṣẹ́ àti ìyà le de ohun ìgbàgbé A rí èyí nínú ohun tí Lásún sọ pé; Ìwọ náà kúkú mọ ipò tí bàbá àti ìyá mi wà lábúlé wa kò rọrùn fún mí láti tọ wọn lọ nígbà tí o jẹ wí pé èmi yìí ní ìrètí wọn oi Síwájú sí òǹkọ̀wé fẹ kí a mọ ọṣẹ́ tí àwọn olórí wa ni lórí ọ̀rọ̀ àìrí iṣẹ́ ṣe oríṣìíríṣìí ìwà ìbàjẹ́ ní o wọ̀pọ̀ ni àwùjọ jíjí ọmọ gbé fífipá bá obìnrin lò pọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Òǹkọ̀wé fẹ́ kí a mọ̀ pé tí olúkúlùkù bá ní iṣẹ́ lọ́wọ́ lẹ́yìn tí wọ́n parí iléìwé àwọn ìwà ọ̀daràn wọ̀nyí yóò di ohun ìgbàgbé láwùjọ Nítorí ọ̀pọ́ tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá finra ni ń wá ọ̀nà àbáyọ láti kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà ọ̀pọ́ ni ń wá ọ̀nà láti pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹbí wọn Ọ̀nà láti ṣe èyí ni ó fa ìwà ọ̀daràn láwùjọ A rí èyí nínú ọ̀rọ̀ tí Àtiòro sọ nígbà tí wọn ni kí o sọ̀rọ̀ ìkẹyìn nígbà tí wọ́n fẹ́ pa á Ẹ̀yìn olórí wà ibi tí ẹ bà mi de ree o Boya bo ba ṣe wí pé ẹ fún mi nísẹ́ nígbà tí mọ nílò iṣẹ́ ní ń o ba máa dé ibi iṣẹ́ burúkú yìí oi Yàtọ̀ sí ọsẹ́ tí àwọn óṣèlú ṣe ni àwùjọ òǹkọ̀wé tún fẹ́ kí a mọ ìwà àwọn olóṣèlú ní àwùjọ Òǹkọ̀wé fi àwọn olóṣèlú hàn gẹ́gẹ́ bí olè gbájúẹ̀ òǹkọ̀wé fí àwọn olóṣèlú hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o ní ifẹ́ ara wọn nìkan tí kò mọ wí pé ebi ń pa ará ìlú Wọn a tún máa kó owó ìlú lọ sí òkè òkun fún ìgbádùn àwọn àti mọ̀lẹ́bí wọn òǹkọ̀wé fí èyí hàn gẹ́gẹ́ bí abàlùjé Òǹkọ̀wé fi yẹ wa wí pé tí àwọn olóṣèlú ba ń kò owó tí wọn ń kò lọ sí òkè òkun silu láti fi ṣe aráyé loore ìṣẹ́ àti ìyà á dínkù ní àwùjọ ṣùgbọ́n owọ́ tí ó yẹ kí o ṣe gbogbo ara ìlú láàànfáni àpò ara wọn nìkan ní wọn ń kò sí A rí èyí nínú ọ̀rọ̀ Àmọ̀pé ẹ̀gbọ́n Gómìnà nígbà tí o ń ba Gómìnà sọ̀rọ̀ ó ní Ìyà ń jẹ́ mẹkunnu ara ń ní ará ìlú ò kò owo ìlú lọ fi pamọ́ sóke òkun oi Kókó mìíràn ní ÌWÀ Ọ̀DARÀN ní àwùjọ Ní àwùjọ lónìí ìṣẹ́ àti ìyà ló sún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọn hu ìwà ọ̀daràn dé bẹ́ẹ̀ ọ̀pọ́ àwọn ọ̀daràn ni àwùjọ ni wọ́n ka ìwé ṣùgbọ́n látàrí àìrí iṣẹ́ ṣe onìkálukú bẹ̀rẹ̀ síni ṣe iṣẹ́ tí ó bá rí láti fi bọ àwọn ẹbi àti ará wọn Nínú ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n òǹkọ̀wé lo Bámidélé láti jẹ kí a mọ wí pé ọ̀pọ́ àwọn ọ̀daràn ni wọn o finú fẹ́dọ̀ máa ṣe iṣẹ́ náà ṣùgbọ́n látàrí àìrí ìkan sè kan wọ́n darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀daràn bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé kò mọ́ iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe tẹ̀lé lẹ́yìn tí ó sí mọ̀ọ́n tán kò le kúrò níbẹ̀ nítorí ó fẹ́ dí ọlọ́la ó fẹ́ kúrò nínú iṣẹ́ àti ìyà A rí èyí nígbà tí Bámidélé sọ fún àwọn ẹgbẹ́ Sílífá Ìrókò pé e Momomo fara mọon gbogbo wọn bú sẹ́rìnín oi Síwájú sí òǹkọ̀wé fẹ́ kí àwọn olórí wà mọ wí pé tí wọ́n ó ba tété wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ ìṣẹ́ àti ìyà tí o ń peléke sí ní àwùjọ àfàìmọ̀ kí àwùjọ máa bàjẹ́ Kókó mìíràn tí a tún rí nínú ìwé eré onítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n ni Ọ̀RỌ̀ ÌFẸ́ A rí ifẹ́ láàárín Bámidélé àti Ṣẹ̀gilọ́lá òǹkọ̀wé fẹ́ kí a mọ wí pé tí ìfẹ́ ti o nípọn bá wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin kò sí bí iṣẹ́ náà ṣe le pọ̀ tó wọn ó ni fira wọn sílẹ̀ wọ́n a máa ṣe nǹkan láti fi ran ara wọn lọ́wọ́ Irú èyí la rí nígbà tí Bámidélé fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀wà títà òǹkọ̀wé fẹ́ kí a mọ wí pé tí ó bá jẹ́ obìnrin mìíràn nibẹ̀ á fi ọkùnrin náà sílẹ̀ látàrí iṣẹ́ tí ó fẹ́ ṣe Ṣùgbọ́n kàkà kí Ṣẹ̀gilọ́lá ṣe èyí ó tún fún un lówó ni A rí èyí nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ó ní; Bámidélé gbà ó na apo ìwé kan sí i jọ̀wọ́ ba mi fa èyí kún èyí tí o ti wa lọ́wọ́ọ́ rẹ̀ Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta naira ló wà nínú rẹ̀ Ohun tí agbára tèmi náà ka nìyíí oi Òǹkọ̀wé fẹ kí a mọ̀ wí pé ifẹ́ àtàtà kì í wo àìdára ara wọ́n Síwájú sí òǹkọ̀wé ní níbi tí ìṣẹ́ àti ìyà ba tí pọ̀jù o máa ń já okùn ìfẹ́ Irú èyí lári láàárín Bámidélé àti Ṣẹ̀gilọ́lá bí ìfẹ́ àárín wọ́n ṣe nípọn tó nígbà tí Bámidélé lówó lọ́wọ́ tán ó gbàgbé Ṣẹ̀gilọ́lá ó bẹ̀rẹ̀ sí ní fowó kó àwọn ọmọ binrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ kiri Ṣẹ̀gilọ́lá di ẹni tí kò mọ̀ọ́n ṣe mọ́ lójú rẹ̀ O di kí o máa rí ìbàjẹ́ ara rẹ̀ A rí èyí nígbà tí Bámidélé ń sọ̀rọ̀ Ó ní Àbẹ́ ò rí i bó ṣe rì ó kàn sanra rẹ̀tẹ̀tè bí adìẹ àbọ́pa Bó bá tilẹ̀ wá rìn hàn yín ń kọ́ Gbiridi ló ń yi bí odó jíbò oi Òǹkọ̀wé fẹ kí a mọ̀ wí pé ìfẹ́ tí ó máa ń tọ́jọ́ ní kí ọkọ àti ìyàwó ní owó láti fí ṣe fújà Kí wọn le ṣe gbogbo nǹkan tí ẹgbẹ́ wọn bá ń ṣe Ṣùgbọ́n tí ìṣẹ́ àti ìyà ba tí pọ̀jù láàárín tọkọ tìyàwó irú ìfẹ́ náà kì í tọjọ́ Kókó mìíràn nibẹ̀ ni OJÚKÒKÒRÒ Nínú ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n òǹkọ̀wé fi ye wa pé iṣẹ́ àti ìyà lápọ̀jù ó máa ń fa ojúkòkòrò Èyí máa ń wáyé nígbà tí ènìyàn ba tí rí ọ̀nà owó kan ṣùgbọ́n látàrí iṣẹ́ àti ìyà tí o tí jẹ́ rí a jẹ́ kí ó máa wa ọ̀nà mìíràn tí owó tí le yọ ju tí àkọ́kọ́ lọ Àpẹẹrẹ ojúkòkòrò ni a rí nínú ìwà Bámidélé Lẹ́yìn tí ó tí ń rówó nínú iṣẹ́ adigunjalè tí o ń ṣe ṣùgbọ́n látàrí ojúkòkòrò ó tún bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ẹ̀yà ara ènìyàn ní èyí tí ó kóba a ní ìgbẹ̀yìn Òǹkọ̀wé fi ń yé wa pé ìwà ojúkòkòrò ko dára àti wí pé ní ọ̀pọ́ ìgbà o máa ń kò ba ènìyàn ỌGBỌ́N ÌṢỌTÀN GẸ́GẸ́ BÍ ÀFIHÀN ÌṢẸ́ ÀTI ÌYÀ Oríṣìíríṣìí ọgbọ́n ìṣọ̀tàn ni òǹkọ̀wé ṣe àmúlò nínú ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìwé eréonítàn ọgbọ́n ìṣọ̀tàn ìsọ̀rọ̀nǹgbèsì ní ó máa ń sábàá wáyé nínú ìwé eréonítàn Yàtọ̀ fún èyí a tún rí àwọn ọgbọ́n ìṣọ̀tàn mìíràn bí í; ọgbọ́n ìṣọ̀tàn amèròọ̀kan ọgbọ́n ìṣọ̀tàn lẹ́tà lílo Ní ode òní àwọn òǹkọ̀wé sábàá máa ń lo àwọn ọgbọ́n yìí Ṣùgbọ́n ní ayé àtijọ́ bí àpẹẹrẹ àwọn òǹkọ̀wé bí Fágúnwà máa ń sábà lọ ọgbọ́n ìsọ̀tàn bí àlọ́ tí ọkùnrin kan a máa sọ ìtàn ìgbési ayé rẹ̀ fún elòmìíràn Ní báyìí a ó wo àwọn ọgbọ́n ìsọ̀tàn náà ni ọ̀kan o jọ̀kan ỌGBỌ́N ÌSỌ̀TÀN ÌSỌ̀RỌ̀ǸGBÈSÌ Ọgbọ́n ìṣọ̀tàn yìí ni o máa ń wáyé nínú eré onítàn bí o tilẹ̀ jẹ wí pé wọn máa ń lọ ọgbọ́n ìsọ̀tàn mìíràn ṣùgbọ́n ọgbọ́n ìṣọ̀tàn yìí ni ó wọ́pọ̀ ju lọ Nítorí nǹkan tí a ba pé ní eré máa ń wáyé láàárín ènìyàn méjì tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ Ọgbọ́n ìsọ̀tàn yìí túmọ̀ sí kí ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta máa tàkurọ̀sọ sí ara wọn òǹkọ̀wé mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe àmúlò ọgbọ́n ìṣọ̀tàn yìí lọ̀pọ̀lọpọ̀ Bákan náà nibẹ̀ òǹkọ̀wé ṣe àfihàn ọgbọ́n ìṣọ̀tàn yìí láti fi iṣẹ́ àti ìyà hàn A rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n ìṣọ̀tàn yìí nígbà tí Bámidélé àti Lásùn ń sọ̀rọ̀ Bámidélé Ìlú Minna; Nibẹ̀ ilẹ̀ àwọn Guwari lo hunun Lásún Bẹ́ẹ̀ nibẹ̀; Bí o ṣe wù mí lọ́kàn mi nìyẹn ó dákẹ́ díẹ̀ Òǹkọ̀wé lo ọgbọ́n ìṣọ̀tàn yìí láti fi ìṣẹ́ àti ìyà hàn lẹ́yìn tí Bámidélé àti Lásùn tí parí iléìwé kò le padà sí ilé nítorí inú ìṣẹ́ àti ìyà tí ó fi àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ sí Ó rò ó láti lọ ìlú Minna bóyá á san fún wọ́n níbẹ̀ A tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n ìsọ̀tàn ìsọ̀rongbèsi tí o fi ìṣẹ́ àti ìyà hàn nígbà tí bàbá Bámidélé àti Olóyè Jégẹ́dẹ́ ń sọ̀rọ̀ Olóyè o sí gbà Alagbà O gba a owo tí yóò fi bẹ̀rẹ̀ owo ohún lọ wa kù báyìí yóò sí tún gba sọ́ọ̀bù Olòyè Bàbá ìjọ o ye mi o ye mi ju ibi ti ẹ o sọ ọ de lọ Elo ganan nibẹ̀ gbogbo owo ti yóò fí bẹ̀rẹ̀ owo yìí oi Òǹkọ̀wé lo ọgbọ́n ìṣọ̀tàn yìí láti fi bí ìṣẹ́ àti ìyà ṣe ń bá ìdílé Bámidélé fínra tó débi wí pé wọn ó rí owó tí wọn yóò kò fún ọmọ wọn láti fi bẹ̀rẹ̀ ẹ̀wà sísè ta Bákan náà òǹkọ̀wé tún lo ọgbọ́n ìṣọ̀tàn yìí láti jẹ́ kí a mọ wí pé tí ìṣẹ́ àti ìyà ba Pòjù kò sí nǹkan tí ènìyàn kò le ṣe èyí ló sún Bámidélé débi òhùn owó tí ó fẹ ṣe A rí èyí nígbà tí òun àti Jáwéṣọlá ń sọ̀rọ̀; Jáwéṣọlá pẹ̀lú ìyàlẹ́nu o só Bámidélé bẹ́ẹ̀ nibẹ̀ mo fẹ́ soogun owó Jáwéṣọlá Bámidélé ìwọ odidin ọmọ kiriyo ọmọ bàbá ijọ kí lọ mu ọ roun oso ṣiṣẹ́ oi ỌGBỌ́N ÌṢỌ̀TÀN LẸ́TÀ Yàtọ̀ fún ọgbọ́n ìsọ̀tàn ìṣòroǹgbèsi á tún rí ọgbọ́n ìsọ̀tàn lẹ́tà lílo tí o ṣe àfihàn ìṣẹ́ àti ìyà Ọgbọ́n ìṣọ̀tàn lẹ́tà kíkọ ní kí ènìyàn fi lẹ́tà bá eniayn sọ̀rọ̀ yálà wọ́n wà ni tòòsí ara wọ́n ni tàbí wọ́n jìnna sí ara wọn òǹkọ̀wé ṣe àmúlò ọgbọ́n ìsọ̀tàn lẹ́tà inú ìwé rẹ̀ Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n láti sọ ipa tí ijọbá kò nínú ọ̀rọ̀ àìrí ìṣẹ́ àti ìyà ní àwùjọ A rí èyí nígbà tí Ṣẹ̀gilọ́lá kò lẹ́tà sí Bámidélé ó ní Bámidélé máa fi àkókò rẹ sófò nibẹ̀ wíwá iṣẹ́ tí kò sí kiri ìlú ẹ̀kọ́ ijọbá àsìko yìí kò náání ọjọ́ ọlá ará ìlú débi wí pé wọn yóò pèsè iṣẹ́ fún wọn oi Òǹkọ̀wé fẹ́ kí a mọ̀ pé àìrí iṣẹ́ yìí ló fà á tí ọ̀pọ́ ènìyàn ṣe ń gbé nínú ìṣẹ́ àti ìyà ỌGBỌ́N ÌSỌ̀TÀN AMÈRÒ ỌKÀN Èyí ní ọgbọ́n ìṣọ̀tàn tí òǹkọ̀wé máa fi ń gbé ìrònú ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ jáde Ní àwùjọ wa lónìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ òǹkọ̀wé nibẹ̀ wọ́n máa ń ṣe àmúlò ọgbọ́n ìṣọ̀tàn yìí òǹkọ̀wé lọ ọgbọ́n ìsọ̀tàn yìí láti jẹ́ kí a mọ ọsẹ́ tí ìṣẹ́ àti ìyà ní lórí àwọn ènìyàn àwùjọ Èyí wáyé nítorí ọ̀pọ́ ènìyàn tí ìṣẹ́ àti ìyà ń ba fínra ní wọ́n máa ń kó ara wọn sínú ìrònú tí wọ́n ba rí àrà tí àwọn olówó ń fi owó dá èyí máa ń mú àwọn tálákà ronú A rí àpẹẹrẹ èyí nígbà tí Bámidélé kúrò nibi ìgbéyàwó ọ̀rẹ́ rẹ náà ṣe máa hu ìwàkíwà Uno gao Lásùn lọ ṣe ìgbéyàwó to larinrin báyìí a bí ẹ wo àwọn èèyàn jankan jankan Àwọn looko lootọ káàkiri orílẹ̀ èdè o dáké díẹ̀ ó ń wó sùn Ẹ wo ìyàwó tí o fẹ́ ó dùn ní wíwò kò sanra jù sẹ́mú sẹ́mú ní gbogbo ara rẹ̀ ṣe O dúró rẹ́gí rẹ́gí A o tilẹ̀ le fi we Ṣẹ̀gilọ́lá tèmi yìí rárá oi Òǹkọ̀wé lo ọgbọ́n ìṣọ̀tàn wọ̀nyí láti fi èrò àwọn ènìyàn àwùjọ hàn lórí ìṣẹ́ àti ìyà lórí àwùjọ O sí ń pé fún ọna àbáyọ sí ọ̀rọ̀ ìṣẹ́ àti ìyà ÌLÒ ÈDÈ Nígbà tí a ba ń sọ̀rọ̀ nípa ìlò èdè ọ̀nà tí òǹkọ̀wé gbà fi èdè sí àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ lẹ́nu ní a fẹ́ wò nínú ìwé eré onítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Ní ọ̀nà kìíní a ó wo èdè tí òǹkọ̀wé fi sí ẹ̀dá ìtàn rẹ lẹ́nu gẹ́gẹ́ bí àfihàn ìṣẹ́ àti ìyà Nígbà tí a o wo èdè tí òǹkọ̀wé fi gbé iṣẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ tí kò jẹ́ kí ó wà sákálá ní ọ̀nà kejì Ní àgbáyé lónìí kí òǹkọ̀wé tó kọ ìwé kan jáde ló tí ní kókó kan tí o ń jẹ ẹ́ lọ́kàn tí o fẹ́ kọ ìwé rẹ̀ lé lórí kókó yìí ní òǹkọ̀wé máa tẹ̀lé láti máa sa èròjà rẹ jọ ní ẹni tere èjì tere Bí àpẹẹrẹ òǹkọ̀wé tí ó fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa óṣèlú a wo èdè tí ó máa ń wáyé láàárín àwọn olóṣèlú kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí kọ ìtàn rẹ̀ Nínú ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n a rí wí pé èdè tí òǹkọ̀wé fi sí àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ lẹ́nu fi àpẹẹrẹ ẹni tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra hàn Nítorí èdè tí a máa ń rí lẹ́nu olówó máa ń yàtọ̀ sí tí ẹnu ẹni tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra ẹni tálákà Ẹni tí ó tó fún ún máa yàtọ̀ sí ẹni tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra A rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ tí ó fi hàn wí pé ìṣẹ́ àti ìyà ń ba àwọn ẹ̀dá ìtàn náà fínra A rí àpẹẹrẹ èdè ìṣẹ́ àti ìyà lẹ́nu Lásùn nígbà tí o ń sọ ipò tí àwọn òbí rẹ̀ wà ní abúlé ó ní Iwọ náà kúkú mọ ipò tí bàbá àti ìyà mí wà lábúlé wa kò rọrun fún mi láti tọ wọ́n lọ nígbà tí o jẹ́ wí pé ẹ̀mí yìí náà ni ìrètí wọn oi Òǹkọ̀wé lo èdè yìí láti jẹ kí a mọ wí pé ìṣẹ́ àti ìyà ń bá àwọn ẹbí Lásùn fínra lábúlé Àti wí pé wọ́n tiraka láti ranan lọ sí ilé ìwé nibẹ̀ èyí tí kò fún un ní ooreọ̀fẹ́ láti lọ bá àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ pàdà Bákan náà ni a tún rí èdè tí o fí ìṣẹ́ àti ìyà hàn nígbà tí Bàbá Bámidélé ń gba ọmọ rẹ̀ ní ìmọ̀ràn kí ó máa ṣe ẹwà ta òǹkọ̀wé fẹ́ kí a mọ̀ wí pé ìdílé tí wọ́n lówó lọ́wọ́ kò ní gba ọmọ wọn ní ìmọ̀ràn kí o máa ṣe ẹwà tà A rí èyí nígbà tí Bàbá Bámidélé ń bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ ó ní Ìdí rẹ rè è tí mo ṣe fimú fínlẹ̀ káàkiri ìlú wa láti ṣe ìwádìí irúfẹ́ iṣẹ́ tí o lè dáwọ́ le mo wá rí wí pé àwọn tí o ń ṣe ẹ̀wà ta nílùú Ẹ̀gbá níbí wọn o tó nǹkan oi Bákan náà ní a tún rí èdè tí òǹkọ̀wé lò tí ó fi ìṣẹ́ àti ìyà ṣe ń ba Lásùn àti àwọn ẹ̀bí rẹ̀ fínra tó débi pé wọn ó rí owó iléìwé rẹ̀ san ó ní Lẹ́ni tó jẹ wí pé bí kì í ba ṣe ẹ̀mí pẹ̀lú sélù bóyá nì i bá parí ẹ̀kọ́ rẹ ní Yunifásítì À bí nígbà tí kò rí owó san ń kọ́ oi Òǹkọ̀wé tún fi sí ẹnu Bámidélé láti fi hàn pé ẹni iṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra lo máa ń da àjọ ọgọrun náírà nítorí ẹni tí o to fún kò ní ranti bóyá ènìyàn tí ẹ máa ń dá àjo kan nígbà tí o jẹ wí pé ìgbà tí ó bá nìlò owó ló máa ń rí A rí èyí nígbà tí Bámidélé ń sọ̀rọ̀ Ọjọ́ wo ganan ní mo fẹ́ ṣe gbogbo èyí da? Ṣe ọgọrun náìrà tí mọ ń dá lájọ lójóójúmọ́ oi Yàtọ̀ fún àwọn èdè tí òǹkọ̀wé fi sí àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ lẹ́nu tí a fi iṣẹ́ àti ìyà hàn A tún rí àwọn ọ̀nà èdè bí owé Àwítúnwí Àfiwé orin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí o fi iṣẹ́ àti ìyà hàn Ní báyìí a máa nú àwọn ìlò èdè náà nibẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan ÒWE Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé òǹkọ̀wé o ṣe àmúlò ìlò èdè tí o pọ̀ síbẹ̀ o lọ àwọn kọ̀ọ̀kan Lára àwọn ìlò èdè tí òǹkọ̀wé lò ní òwe Yorùbá ni ìlú àgídìgbo ní òwe ọlọgbọ́n ni í jo ọ̀mọ̀ràn ní i sì í mọ̀ ọ́n Òǹkọ̀wé ṣe àmúlò òwe tí o fi ìṣẹ́ àti ìyà hàn àpẹẹrẹ A rí òwe nígbà tí ìṣẹ́ àti ìyà pọ̀ ní ìdílé Bámidélé lẹ́yìn tí o parí ilé ìwé tí kò rí iṣẹ́ Bàbá rẹ̀ pa òwe ó ní Àlẹ́lẹwọ́ ẹni kì í sá à tan nibẹ̀ jẹ oi Òǹkọ̀wé lo òwe yìí wí pé tí ènìyàn kò ba rí iṣẹ́ ọba ṣe tí ó sí ń ṣiṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ̀ o máa ń din iṣẹ́ àti iya ku Nítorí náà yóò dára kí Bámidélé máa ṣiṣẹ́ ara a rẹ dípò kí o máa fi àkókò sòfò A tún rí òwe mìíràn tí òǹkọ̀wé fi hàn pé iṣẹ́ àti ìyà ba pọ lápọ̀jù oríṣìíríṣìí èrò ní o máa ń wa sí ọ̀kan ènìyàn A rí àpẹẹrẹ òwe yìí nígbà tí Bámidélé ń sọ̀rọ̀ ó ní Ẹni tí o mo ibi tí ẹgbẹ́ rẹ̀ ti la eré lọ máa sá ku A tún rí òwe mìíràn nígbà tí Bámidélé ń sọ̀rọ̀ òǹkọ̀wé fi hàn pé bí o pé tí iṣẹ́ àti ìyà tí ń ba ènìyàn fínra nibẹ̀ ọjọ́ kan a dára fún ẹni náà òǹkọ̀wé ń fi òwe yìí wàásù fún ẹni tí iṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra Ó ní Bí orí ba pé nílẹ̀ aa dire Yàtọ̀ fún òwe wọ̀nyí òǹkọ̀wé tún lọ òtòpọ̀ òwe Èyí ni kí ènìyàn máa pa òwe méjì tàbí jú bẹ̀ẹ́ lọ ni ẹ̀ẹ̀kan náà Bí àpẹẹrẹ Ẹ̀dá to gbẹ́yìn larẹwà ń rin jẹpẹ́ lọ́mọ́ ọlọba ń yan ìgbà onípẹ̀lé kì í fọ àwo onípẹ̀lẹ́ kì í fa ya Ohun a fẹ̀sọ̀ mú Kì í bàjẹ́ ohun a fagbára mú kókó nibẹ̀ i le oi Òǹkọ̀wé fi òwe yìí sí ẹnu jáwésọlá láti fi hàn pé tí ìṣẹ́ àti ìyà bá pọ́ju ó di dandan kí ènìyàn nibẹ̀ suuru kí o máa kánjú wa owó ÀFIWÉ Oríṣìí àfiwé méjì ní ó wa bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé oríṣìí àfiwé kan ní òǹkọ̀wé ṣe àmúlò Àfiwé ní kí ènìyàn fi ohun méjì tí a mọ̀ wé ara wọn A rí àfiwé tààrà nínú ìwé Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n nígbà tí Bámidélé ń ba Tutù sọ̀rọ̀ Míníníní ní o tutù bí omi àjípọn lódò oi Òǹkọ̀wé fi àfiwé yìí sẹnu Bámidélé láti fi hàn pé kò sí bí iṣẹ́ àti ìyà ṣe le pọ̀ tó kí ènìyàn máa dá nǹkan tí o dára mọ ỌFỌ̀ Èyí jẹ èdè ìsẹ̀nbáyé Yorùbá tí ó wa lẹ́nu àwọn babańlá wa Wọ́n máa ń lò ó fún nǹkan rere tàbí burúkú Bí àpẹẹrẹ Ọ̀kan soso póró Àwo igún Ó da fún igún Tì ń tọ̀run bọ wa sílẹ̀ ayé Aràbádáa wo àkàlà oi ÌHÀ TÍ ÒǸKỌ̀WÉ KỌ SÍ ÌṢẸ́ ÀTI ÌYÀ NÍNÚ ÌWÉ ERÉONÍTÀN BÁMIDÉLÉ ẸLẸ́WÀ SÀPỌ́N Kí òǹkọ̀wé tọ kọ ìtàn tàbí eré kan sí ìta fún ìgbádùn àwọn ènìyàn o tí ní kókó kan tí o ń jẹ òǹkọ̀wé bẹ́ẹ̀ lọ́kàn Tí òǹkọ̀wé bá ka ìwé kan fún àpẹẹrẹ ó le wo kókó inú ìwé náà gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbàjẹ́ tí o ń lọ láwùjọ ó lè jẹ igabalé àwọn olóṣèlú Adebayo Adébọ̀ gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀tàn ìwé eré onítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n kò dì ì di gbé iṣẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ láti wo ìhà tí ó kò sí ìṣẹ́ àti ìyà ní àwùjọ ó le jẹ́ nǹkan mìíràn ló jẹ ẹ lọ́kàn Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń ṣe ìtúpalẹ̀ ó di dandan kí a wo ìhà tí òǹkọ̀wé kọ sí ìṣẹ́ àti ìyà Nínú ìfọ̀rọ́wánilẹ́nuwo ti a ṣe pẹ̀lú òǹkọ̀wé o ti yé wa pé oun o gbé ìwé náà kalẹ̀ láti wo iṣẹ́ àti ìyà Ṣùgbọ́n báyìí gẹ́gẹ́ bí ìbéèrè tí a bí i ó ṣàlàyé pé ìhà tí kò dára lọ n kọ sí ìṣẹ́ àti ìyà àti wí pé nǹkan tí o ń ṣokùnfà ìṣẹ́ àti ìyà láwùjọ kò ju àwọn olórí tí kò dára tí a ni orílẹ̀ èdè yìí lọ O ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n parí ni wọn o rí iṣẹ́ ṣe ni èyí tí o máa ń yọrí sí ìwà ọ̀daràn gbogbo bí jíjí ọmọ gbé jija olè fifi pa bá obìnrin lo pọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Òǹkọ̀wé fí èyí hàn nígbà tí o fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ rẹ àtòrò nígbà tí wọ́n fẹ́ pa a tí wọn ní kí ó sọ ọ̀rọ̀ ìkẹyìn ó ní Ẹ̀yìn olórí wa ibi ti ẹ ba mi de e ree o Boya bo ba ṣe wí pé ẹ fún mí nísẹ́ nígbà tí mo nílò iṣẹ́ ni ń ó ba máa de ibi iṣẹ́ burúkú yìí oi Òǹkọ̀wé fi gbólóhùn yìí sí ẹnu ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ láti jẹ́ kì í a mọ wí pé iṣẹ́ àti ìyà lápọ̀jù ló máa ń sún ènìyàn débi ìwà burúkú gbogbo nǹkan wọ̀nyí sí ń wáyé látàrí àwọn olórí tí kò dára tí a ní Ṣùgbọ́n òǹkọ̀wé fi ìgbé ayé Bámidélé wé ìgbé ayé tí iṣẹ́ àti ìyà ń ba fínra Nínú ìfọ̀rọ̀wanílẹ́nuwo tí a ṣe pẹ̀lú òǹkọ̀wé ṣàlàyé pé ìṣẹ́ àti ìyà lo sún Bámidélé débi kí ó máa ṣe ẹ̀wà ta Ó ṣàlàyé pé ni àwùjọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lónìí púpọ̀ nínú àwọn ọ̀dọ̀ ni wọn ó rí iṣẹ́ Nípasẹ̀ èyí wọ́n bẹ̀rẹ̀ síní ṣe iṣẹ́ ti wọ́n ba rí Irú àpẹẹrẹ èyí ni òǹkọ̀wé fi hàn nínú ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ Bámidélé; o ku ìgbìyànjú Ibi taa de lórílẹ̀ èdè yìí lo rí yìí o a fi kí Ẹlẹ́dàá sàánú wa bí ìjọba ba kọ̀ tí wọn o náání ará ìlú tí wọ́n kọ ti wọn ò fún ọ níṣẹ ìdí rẹ̀ ré é tí mo ṣe finnú fínlẹ̀ káàkiri ìlú wa láti ṣe ìwádìí irúfẹ́ iṣẹ́ tí o le dáwọ́ lé Mo wá rí wí pé àwọn tí wọn ń ṣe ẹwà tà nílùú Ẹ̀gbá níbi wọn o tó nǹkan oi Bákan náà ní òǹkọ̀wé ṣàlàyé pé kì í ṣe gbogbo àwùjọ ni ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra Òǹkọ̀wé jẹ́ kí a mọ̀ wí pé àwọn olórí ò bìkità bóyá ebi ń pa àwọn ara ìlú Ara wọ́n nìkan ní wọ́n mo Ó tún ṣe àlàyé síwájú sí pé owó tí ó yẹ kí o ṣe àwọn ará ìlú ní àǹfààní òkè òkun ní wọ́n ń kówó lọ Fún ìdí èyí ìṣẹ́ àti ìyà á máa pọ̀ sí ni àwùjọ ni O fi èyí hàn nínú ìwé rẹ̀ nípa ìwà Gómìnà O dára bí o ba de ìlú ọba lohunun sọ fún ma ma yin wí pé Miliọọnu mẹ́wàá owó lọ wà nínú bagi yẹn sọ fún un kí ó fi miliọọnu méjì méjì sí ilé ìfowó pamọ́ lorúkọ ìwó àti ẹ̀gbọ́n rẹ Bákan náà ní òǹkọ̀wé ṣàlàyé pé ìṣẹ́ àti ìyà ló máa ń sun ènìyàn dé bí ìwà tí kò dára Ó lo Bámidélé láti fi ọsẹ́ tí ìṣẹ́ àti ìyà ni lórí àwọn ọ̀dọ́ hàn Bámidélé tí ó parí iléìwé tí kò rí iṣẹ́ Ó bẹ̀rẹ̀ sí ni ta ẹ̀wà níbi ẹ̀wà tí o ń ṣe tà ni ọ̀rẹ́ rẹ tí fi iṣẹ́ adigunjalè lọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà èyí ló mú un bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí Ní ìgúnlẹ̀ a lè sọ pé ọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́ àti ìyà tó gbòde kan ló ṣokùnfà àtẹ̀jáde ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Òǹkọ̀wé ṣàlàyé okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi hàn Ó fihàn pé òǹkọ̀wé pàápàá kò faramọ ibi ti ìṣẹ́ àti ìyà bá àwùjọ dé ó sì ń pè fún àtúnṣe ní kíákíá ORÍ KARÙNÚN ÀBÁLỌBÁBỌ̀ ÌFÁÀRÀ Yorùbá bọ̀ wọ́n ni bí ọkọ ba ròkun tó bá rọ̀sà á fabọ̀ sébùté bẹ́ẹ̀ ni kó sí ohun tó ni ìbéèrè tí kì í ni òpin Orí karùnún iṣẹ́ yìí ni a ti sọ abọ ìwádìí ni ṣókí A sọ̀rọ̀ nípa àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ yìí ní ìparí a fún àwọn asèwádìí ọjọ́ iwájú ni ìmọ̀ràn tí a sí se ìkádìí iṣẹ́ yìí pẹ̀lú ÌSỌNÍṢÓKÍ ÀBỌ́ ÌWÁDÌÍ Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí a tí sá sóke sódò láti rí i wí pé iṣẹ́ ìwádìí yìí kẹ́sẹjarí Ohun tí a gbé jẹ̀wò ní iṣẹ́ àti ìyà nínú ìwé eré onítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n tí Báyọ̀ Adébọ̀ kọ A ṣe àmúlò tíọ́rì Ṣosíọ́lọ́jì tí o tẹ̀lé ìlànà Lẹ́yìn tí a ṣe ìwádìí ó hàn gbangba pé ìṣòro ńlá ni ìṣẹ́ àti ìyà ń mú bá àwùjọ wa pàápàá jùlọ àwùjọ tó bí ìwé eré onítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí a ṣe àgbéyẹ̀wò nǹkan tí o ń fa ìṣẹ́ àti ìyà ní àwùjọ wa pàápàá jùlọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà Lára rẹ̀ ni àwọn òṣèlú wa A rí i wí pé ìhùwàsí àwọn òṣèlú wa kò fi ààyè sílẹ̀ fún ìgbáyégbàdùn àwọn ará ìlú kò sí iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọn parí ilé ẹ̀kọ́ wọn nígbà tí kò sí ọ̀nà àti jẹnu fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ sí hùwà ọ̀daràn àti oríṣìíríṣìí ìwà àìtọ́ mìíràn láti fi rówó sayé Bákan náà iṣẹ́ ìwádìí yìí ṣe àfihàn àtubọ̀tán ìṣẹ́ àti ìyà ní àwùjọ wa gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú ìwé eréonítàn náà Bí àpẹẹrẹ àpọ̀jù ìṣẹ́ àti ìyà ni ó mú Bámidélé Àkòro Kòǹkọ̀sọ̀ Àkànjí máa hu ìwà ọ̀daràn fífọ́ báǹkì kíkó ilé títa ẹ̀yà ara ènìyàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ní àwùjọ wa a rí àwọn ọ̀daràn lórísirísí tí o jẹ́ wí pé àtíjẹ́ àtimu ló sùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ́n débi ìwà ọ̀daràn tí wọn ń hù A rí àwọn ènìyàn bí Bámidélé ni àwùjọ wa tí wọn parí iléìwé ṣùgbọ́n látàrí wí pé wọn ó rí iṣẹ́ ṣe wọ́n dẹni tó ń hùwà ọ̀daràn kí wọ́n le rí owo fi bọ́ ẹbí àti ara wọn Síwájú sí i ọ̀pọ́ àwọn òṣèlú ni wọ́n ń kò owó tí ó yẹ kò ṣe àwùjọ láàǹfàní lọ sókè òkun Ní àwùjọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà a rí àwọn òṣèlú bí Gómìnà tí o ń kò owó ìlú lọ fí pamọ́ sí òkè òkun tí ìṣẹ́ àti ìyà sí ń náà àwọn ènìyàn àwùjọ bí ẹni náà asọ òfì Síwájú sí i iṣẹ́ ìwádìí yìí dabaa ọ̀nà àbáyọ sí ìṣẹ́ àti ìyà ní àwùjọ wa Lára rẹ ní pé kí ijọbá orílẹ̀èdè yìí wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àìrí iṣẹ́ tí o ń fi ojoójúmọ́ péleké ni àwùjọ Bákan náà o yẹ kí ìjọba wa wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣe àdá sí ọrọ̀ajé olókowò aládàńlá bákan náà kí àwọn ijọbá wa máa fi owó ìlú ṣe nǹkan tó bá wúlò fún gbogbo àwùjọ kí wọn yé kówó ìlú lọ sí òkè òkun mọ Bákan náà kí wọ́n pèsè iṣẹ́ fún gbogbon ènìyàn kí ìṣẹ́ àti ìyà le dín ku ni àwùjọ wa ÀMÚYẸ ÀTI ÀLÉÉBÙ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Onírúurú bí asọ alágẹmọ̀ ní àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí yìí tí mu kí ìmọ̀ wa gbòòrò sí nípa ìṣẹ́ àti ìyà tí o ń bá àwùjọ funra A rí oye èyí nípa wíwò àwọn tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra nínú ìwé eré onítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Àwọn bí í Bámidélé a sí wo bí ìṣẹ́ àti ìyà yìí ṣe nípa lórí wọn Báyọ̀ Adébọ̀ fún wa ní àǹfààní láti mọ ìdí tí ìṣẹ́ àti ìyà fi pọ̀ ní àwùjọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà o di ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà ru ìjọba Bákan náà ni ó sì wá ọ̀nà àbáyọ fún wa Èyí nìkan kọ lára àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí yìí ni pé òǹkọ̀wé mọ ìwé eré onítàn kọ dáradára Yorùbá bọ wọ́n ní a kì í mọ̀ọ́n gún mọ̀ọ́n tẹ̀ kí iyán ewúrà máa ni kókó Bẹ́ẹ̀ ni a kì í mọ̀ọ́n wẹ̀ kí a wẹ́ omi òkun já Bí o tí wù kí iṣẹ́ ènìyàn ka dára tó kò ní sáì ní kùdìẹ̀kudiẹ kan tàbí òmíràn Ohun tí a lè tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí kùdìẹ̀kudiẹ inú ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n ní pé òǹkọ̀wé kò ṣe àmúlò ọnà èdè tí ó máa ń mú kí iṣẹ́ lítíréṣọ̀ dùn dára dára bákan náà ó yẹ kí èdè tí òǹkọ̀wé fi sí ẹnu àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ kò ìṣẹ́ àti ìyà hàn Bí àpẹẹrẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni Òkédìji tí jẹ́ kí a mọ̀ pé ìṣẹ́ àti ìyà ń ba àwọn òṣìṣẹ́ fínra nínú Rẹ́rẹ́ Rún ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orin Èrò tí ń ro jejeeje ojeeje Ewi fún iya mi ojeeje Ẹyin to fi sílẹ̀ ojeeje Ní ìgúnlẹ̀ òǹkọ̀wé ìwé eré onítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n kó ènìyàn mọ́rà ó sí farabalẹ̀ láti jẹ́ kí ìmọ̀ wa kún sí í lórí ọ̀rọ̀ ìṣẹ́ àti ìyà tí o ń lọ ní àwùjọ Asínilétí alanilóye ni ìwé náà jẹ́ Bí òǹkọ̀wé kò tile faramọ́ ìwà Bámidélé síbẹ̀ ó di ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà ru àwọn aláṣẹ wa tí kò náání ìlọsíwájú àwọn ọ̀dọ́ ÌMỌ̀RÀN FÚN ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Ìmọ̀ràn mi fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ onímọ̀ àti onífẹ̀ẹ́ èdè Yorùbá ní pé kí wọ́n máa ṣe ìwádìí lórí àwọn ìwé eréonítàn Yorùbá lóríṣirísi àti àwọn ìwé eréonítàn pẹ̀lú èyí yóò jẹ́ kóríyá fún àwọn òǹkọ̀wé Yorùbá tí yóò sì jẹ́ kí àwọn òǹkọ̀wé èdè Yorùbá bọ̀ sí i Bákan náà ní yóò mú ìdàgbàsókè bá èdè àti àwùjọ Yorùbá lápapọ̀ Síwájú sí i kí àwọn aṣèwádìí ọjọ́ iwájú kíyèsí àwọn abala tí ó sẹ́kù nínú ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Àwọn aṣèwádìí ọjọ́ iwájú le wo kókó inú ìwé eré onítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Mélòó ní ọ̀káńjúà fẹ́ mu nínú omi òkun ní iṣẹ́ tí ó kù tí aṣèwádìí lè ṣe fún ìdí èyí a rọ àwọn aṣèwádìí ọjọ́ iwájú kí wọn tẹ̀síwájú lórí ṣíṣe ìwádìí lórí ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Ní àfikún a gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá ní ìmọ̀ràn pé ìwádìí yòówù tí wọn bá ṣe kí wọn máa fi ara balẹ̀ ṣe ìwádìí wọn dáadáa nítorí èyí nìkan ní ọ̀nà àbáyọ tí wọn lè gba láti tú iṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò lórí iṣẹ́ ìwádìí yòówù tí wọn ba ń se ÌKÁDÌÍ Yorùbá bọ̀ wọ́n ni bí a ba gbá ilé ti a gbá ìta ààtàn là á darí rẹ̀ sí A ti gbìyànjú láti wo ìṣẹ́ àti ìyà nínú ìwé eréonítàn Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n A wo okùnfà ìṣẹ́ àti ìyà a sì tún wo ọsẹ́ tí ìṣẹ́ àti ìyà ní lórí àwùjọ àti ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà Èyí nìkan kọ́ a wo àwọn kókó ìlò èdè ẹ̀dá ìtàn ibùdó ìtàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ bí wọn ṣe fi ìṣẹ́ àti ìyà hàn Fún ìdí èyí ìgbàgbọ́ wa ni wí pé ẹnikẹ́ni tó bá ka iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí yóò ni ìmọ̀ nípa ọ̀nà tí àwùjọ lè gbà kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà tí ó gba àwùjọ kan báyìí ÀSOMỌ́ ABẸ́NÀÌMỌ̀ ADÉBÁYỌ̀ ADÉBỌ̀ ÀSOMỌ́ ABẸ́NÀÌMỌ̀ ADÉBÁYỌ̀ ADÉBỌ̀ ÀTI OLÙWÁDÌÍ ÀKÓJỌ ORÚKỌ ÌWÉ Adeyẹ́mí O Tíọ́rì Lítíréṣọ̀ ni Èdè Yorùbá Ìjẹ̀búÒde Sebiotimọ Ajíbóyè O Lítíréṣọ̀ Yorùbá Ìlọrin Akànmídù Ìkẹjà Aliu Báyọ̀ A Bámidélé Ẹlẹ́wà Sàpọ́n Ìbàdàn Ògúndèjì PA Eré Oníṣẹ́ Yorùbá nínú ÌṢẸ̀DÁ Ọ̀RỌ̀ORÚKỌ NÍ Ẹ̀KAÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ ỌLÁNÍRAN ỌLÁÍDÉ APÁ KAN IṢẸ́ ÀṢEKÁGBÁ FÚN Ẹ̀KỌ́ ÀKÀGBOYÈ NÍNÚ ÌMỌ̀ ÌPÌLẸ̀ Ẹ̀DÁ Bii Eè NÍNÚ ÈDÈ YORÙBÁ NÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ YUNIFÁSÍTÌ ÌLỌRIN ÌLỌRIN NÀÌJÍRÍÀ OṢÙ IGBE ÌFỌWỌ́SÍ Iṣẹ́ àkànṣe yìí ni a ti kà tí a sì rí i pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè àti Èdè Nàìjíríà Yunifásítì Ìlọrin Ìlọrin AYA ADÉKẸ́YÈ F ỌJỌ́ ALÁBÒÓJÚTÓ OLÙYẸ̀WÒ ÌTA ỌJỌ́ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N ỌJỌ́ OLÓRÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁ ÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ÌFISỌRÍ Mo fi iṣẹ́ àṣekágbá yìí sọrí Ọlọ́run ọba fún àtìlẹ́yìn rẹ̀ Bákan náà mo fi sọrí àwọn obi mi Alàgbà àti aya Ọládàpọ̀ Ọláníran ÌDÚPẸ́ Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọba awímáyẹhùn asọ̀rọ̀mátasé ò ránmọ níṣẹ́ fàyà tì í ọba àìkú ọba aìsá ají pọjọ́ ikú dà ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin ohun gbogbo fún mí mú mi bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí láyọ̀ tí ó sì tún jẹ́ kí ń pari láyọ̀ mo yíka ọ̀tún mo yíka òsì mo kan sárá sí ọ̀gá ògo Bákan náà mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn obi mi tí ó tukọ̀ mi wá sáyé Alàgbà àti aya Ọládàpọ̀ Ọláníran fún ìnáwó nára yín lórí mi láti lè jẹ́ kí ń kọ́ ẹ̀kọ́ yìí lágbára Ọlọ́run oúnjẹ ọmọ kò ní korò lẹ́nu yín ẹ ṣeun mo dúpẹ́ Ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ alábòójútó iṣẹ́ àṣekágbá yìí Aya Adékẹ́yè Mo kí i yín fún ìtọ́sọ́nà àti ìgbani níyànjú yín nígbà gbogbo láti lè mú kí iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí kẹ́sẹ járí lágbára Ọlọ́run gbogbo ìdáwọ́lé yín ni yóò yọrí sí rere àánú Ọlọ́run kò ní fi ẹ̀yin àti ìdílé yín sílẹ̀ Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ abẹ́nàìmọ̀ mi fún àtìlẹ́yìn wọn lórí iṣẹ́ àkànṣe yìí kí Ọlọ́run bá mi dúró tì wọ́n Síwájú sí i ọpẹ́ mi lọ sọ́dọ̀ Olóyè àti ayaAdáramọ́lá fún àtìlẹ́yìn wọn lórí iṣẹ́ àkànṣe yìí lágbára Ọlọ́run gbogbo ìdáwọ́lé yín ni yóò yọrí sí rere àánú Ọlọ́run kò ní fi yín sílẹ̀ Bákan náà ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ Alàgbà àti aya Ọládèjì fún àdúrótì wọn mo gbàdúrà kí Ọlọ́run dúró tì yín Ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi kí Ọlọ́run jẹ́ kí a pẹ́ fún ara wa Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àfẹ́sọ́nà mi Adáramọ́lá Morẹ́nikéjì fún àtìlẹ́yìn rẹ̀ Bákan náà mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀gbẹ́ni Désọ́lá Sàlámì fún ìrànlọ́wọ́ wọn lórí iṣẹ́ àkànṣe yìí Ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ aya Sàlámì ẹ ṣé púpọ̀ Mo sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi Akínpẹ̀lú Abímbọ́lá Adédèjì Adéníkẹ̀ẹ́ Díẹ̀kọ́lá Ọláníkẹ̀ẹ́ àti àwọn tí a kò lè dárúkọ ÀṢAMỌ̀ Èròǹgbà iṣẹ́ àkànṣe yìí ni bí a ṣe ń ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà Nígbà tí a ó ṣe àfiwé ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà sí Yorùbá àjùmọ̀lò Nínú iṣẹ́ yìí a ó wo oriki tí àwọn onímọ̀ fún mọfọ́lọ́jì ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ bákan náà a ó wo fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà àti àwọn ìyàtọ̀ tí a lè bá pàdé nínú bí a ṣe ń ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà sí Yorùbá àjùmọ̀lò ÀTẸ ÀKÓÓNÚ Àkọlé Ìfọwọ́sí Ìfisọrí Ìdúpẹ́ Àṣamọ̀ Àtẹ Àkóónú ORÍ KÌNÍNNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Ìfáàrà Èrèdí iṣẹ́ ìwádìí yìí Ibi tí ìwádìí gbòòrò dé Ọgbọ́n ìwádìí Àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí yìí Ètò ìwádìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN Ìfáàrà Èdè Ẹ̀kaÈdè Ẹ̀yà Ẹ̀ka Ìgbómìnà Ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ Mọfọ́lọ́jì ORÍ KẸ́TA FONỌ́LỌ́JÌ ÈDÈ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ SÍ Ẹ̀KAÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ Ìfáàrà Fonọ́lọ́jì Ẹ̀kaÈdè Ìgbómìnà Ètò ìró ní ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà Ìró Kọ́ńṣónáǹtì ní Ẹ̀kaÈdè Ìgbómìnà Ìró Fáwẹ́lì ní Ẹ̀kaÈdè Ìgbómìnà Ìró Ohùn Ìgúnlẹ̀ ORÍ KẸ́RIN ÌṢẸ̀DÁ Ọ̀RỌ̀ORÚKỌ NÍ Ẹ̀KAÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ Ìfáàrà Lílo àfòmọ́ Kíkan ọ̀rọ̀ pọ̀ Ṣíṣe àpètúnpè Ọ̀rọ̀ àyálò Ìgúnlẹ̀ ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ Ìfáàrà Ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí Àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí yìí Ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́iwájú Ìkádìí Àkójọ orúkọ ìwé ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀SẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌFÁÀRÀ Ohun tí a fẹ́ gbéyẹ̀wò nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà èyí tí a lè rí ní apá kan ìpínlẹ̀ àti ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà Nínú iṣẹ́ yìí ni a ó ti ṣe àlàyé ní kíkún lórí ohùn tí mọfọ́lọ́jì jẹ́ ní pàtó àti àwọn ìgbésẹ̀ àti ìlànà tó wà lábẹ́ mọfọ́lọ́jì Tí a bá wo gbólóhùn a ó rí oríṣìíríṣìí àwọn ìgbésẹ̀ àti ètò tó waye àti ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì síntáàsì mọfọ́lọ́jì àti sẹ̀máńtíìkì ló pé sínú gbólóhùn tí wọ́n sì ní ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀lé Ṣùgbọ́n ní ti iṣẹ́ ìwádìí yìí ìgbésẹ̀ kan gbòógì ni a fẹ́ yẹ̀wò èyí ni ìgbésẹ̀ mọfọ́lọ́jì èyí tí ó jẹ́ ẹ̀kọ́ nípa ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ Ó ní àwọn ìlànà àti ètò kan pàtó tó de ìṣẹ̀dá wọn nínú ọ̀rọ̀ ìlànà àti ètò náà ni a fẹ́ gbéyẹ̀wò nínú ìwádìí yìí Àfiwé àwọn ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà ìgbésẹ̀ mọfọ́lọ́jì bí i lílo àfòmọ́ ṣíṣe àpètúnpè kíkan ọ̀rọ̀ pọ̀ àti ṣíṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ àyálò wà lára ohùn tí iṣẹ́ ìwádìí yìí dálé lórí Bákan náà irú àwọn ìró tí a lè bá pàdé nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà bí i ìró kọ́ńsónáǹtì ìró fáwẹ́lì àti ìró ohun ni a o yóò nínú iṣẹ́ àkànṣe yìí ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé oríṣìíríṣìí ni àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá nítorí náà iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò jẹ́ ọ̀kan pàtàkì láti mọ èdè Ìgbómìnà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kaèdè tó súyọ lábẹ́ èdè Yorùbá A kò tí ì rí iṣẹ́ kan gbòógì tó dá lórí ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà fún ìdí èyí iṣẹ́ ìwádìí yìí yo le è fún wa ní òye kíkún lórí iṣẹ́ náà IBI TÍ ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní kò sí bí iṣẹ́ tí lè gbòòrò tó kí ó máa ní ibi tí ààlà rẹ̀ yóò mọ Tí a bá wo àkọlé iṣẹ́ ìwádìí yìí ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà A ó wo àwọn ìró tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà bí i; ìró kọ́ńsónáǹtì ìró fáwẹ́lì àti ìró ohùn Ọ̀kan lára ohùn tí ó jẹ wá lógún nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni ṣíṣe àfiwé mọfọ́lọ́jì Yorùbá àjùmọ̀lò àti mọfọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ Àwọn ìgbésẹ̀ kan ni mo tẹ̀lé láti ṣe ìwádìí lórí iṣẹ́ yìí Láti ní òye kíkún lórí iṣẹ́ yìí mo ṣe akitiyan láti ṣe ìwádìí lodo onírúurú ènìyàn tí mo lò gẹ́gẹ́ bí abẹ́nàìmọ̀ fún àṣeyọrí tó yè kooro lórí iṣẹ́ yìí Síwájú si i mo lo ìlànà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò níbẹ̀ ni mo ti lo ẹ̀rọ gbohùngbohùn láti fi gba ohùn abẹ́nàìmọ̀ sílẹ̀ Mo ṣe àtòjọ ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí aṣẹ̀dá ní olóríẹ̀ka èdè Yorùbá àjùmọ̀lò lóríṣiríṣi èyí tí abẹ́nàìmọ̀ mi sì sọ fún mi bí wọ́n ṣe ń pè wọ́n ní ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà Bákan náà mo lọ si iyàrá ìkàwé láti ka onírúurú ìwé lórí iṣẹ́ ìwádìí yìí àwọn ìwé yìí ràn mí lọ́wọ́ púpọ̀ Ní àkótán mo ṣe àmúlò àtọ̀jọ oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ èyí ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ìtúpalẹ̀ iye ìró kọ́ńṣónáǹtì àti ìró fáwẹ́lì tí ó wà ní ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò wúlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ iwájú tí wọ́n fẹ́ ṣe ìwádìí lórí àkọlé tó farapẹ́ èyí bákan náà ni máa tun sọ̀rọ̀ lórí bí a ṣe ń ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ nínú olórí ẹ̀kaèdè Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé kò tí ì sí ẹnìkan pàtó tí ó ti ṣiṣẹ́ lórí bí a ṣe ń ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ ní ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà nítorí náà iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò làwá lọ́yẹ̀ lórí ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà Tí a bá wo mọfọ́lọ́jì nínú èdè a ó rí i pé ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára gírámà èdè tí kò yọ Yorùbá sílẹ̀ Oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni Yorùbá ń gbà láti ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun èyí bẹ̀rẹ̀ láti orí lílo àfòmọ́ kíkan ọ̀rọ̀ pọ̀ ṣíṣe àpètúnpè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ṣùgbọ́n ohùn tí ó jẹmí lógún jùlọ ni bí wọ́n ṣe ń ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà Síwájú sí i mo má a wo àwọn ìró inú ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà àti bí wọ́n ṣe ń jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ wọn Àfiwé ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní ẹ̀kaẹ̀dá Ìgbómìnà àti olórí ẹ̀kaèdè Yorùbá àjùmọ̀lò náà kò ní gbẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ÈTÒ ÌWÁDÌÍ Èròǹgbà iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti ṣe àfiwé àwọn ọ̀nà tí à ń gbà ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní olórí ẹ̀kaèdè Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà A pín iṣẹ́ ìwádìí yìí si ọ̀nà márùnún tí mo sì ṣe ìfáàrà lórí ohùn tó pilẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí Nínú rẹ̀ ni a ti sọ èrò ọkàn olùwádìí ní pàtó tí ó fi yan iṣẹ́ ìwádìí náà láàyò ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà A tún wo ibi tí ìwádìí gbòòrò dé àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí yìí Nígbà tí ètò ìwádìí fúnra rẹ̀ kò gbẹ́yìn Nínú orí kejì ni a ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò lórí aayan ọ̀mọ̀ràn Bákan náà ni a ó tún ṣe àgbéyẹ̀wò ohùn tí èdè jẹ́ ẹ̀kaèdè àti ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà Síwájú sí i ní orí kẹ́ta ni a ó ti sọ̀rọ̀ nípa fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà àti àwọn ìró nínú ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà Ní àfikún nínú orí kẹ́rin ni a ti ṣiṣẹ́ lórí àfiwé ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà Orí karùnún jẹ́ àgbálọgbábọ̀ nínú èyí ni a ó ti rí àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí yìí ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú àti ìkádìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN ÌFÁÀRÀ Ní orí yìí ni a ti máa sọ̀rọ̀ lórí ohùn tí èdè jẹ́ àwọn ẹ̀kaèdè tí a lè rí lábẹ́ èdè Yorùbá bákan náà a ó sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè Yorùbá Síwájú sí i a ó ṣàlàyé ní kíkún lórí àwọn ọ̀nà tí a máa ń gbà láti ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ tuntun nínú èdè Yorùbá èyí tí a mọ̀ sí mọfọ́lọ́jì EDE Gẹ́gẹ́ bí oriki tí Fájẹ́nyọ̀ fún èdè ó ní Èdè ni ọ̀nà tí à ń gbà fi èrò wa hàn sí ayé gbọ́ ohùn náà sì ni ìró tí a sọ jáde láti enu tàbí tí a kọ sílẹ̀ tí ó fi èrò ọkàn wa hàn tí ó sì ní ìtumọ̀ sí ẹni tí ó ń gbọ́ ọ tàbí kà á Bákan náà Adéyínká náà fún èdè ní oriki ó ní; Èdè ni a lè pè ní ìlànà tí ẹ̀yà ènìyàn kan ń gbà láti fi èrò inú wọn hàn yálà nípa kíkọ èrò náà sílẹ̀ tàbí nípa sísọ jáde lẹ́nu lọ́nà tí ó fi lè yé gbogbo ènìyàn tí ó ń lo ìlànà náà Bí a ṣe rí àwọn onímọ̀ nílẹ̀ Yorùbá tí wọ́n fún èdè ní oríkì bẹ́ẹ̀ ni àwọn onímọ̀ Gẹ̀ẹ́sì kò gbẹ́yìn Lára wọn ni a ti rí tí ó sọ wí pé Ohun tí ń sọ ni pé; Èdè kì í ṣe fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀ nìkan nípa àkókò àti ohùn mìíràn Bákan náà ni ó tún jẹ́ kí àjọṣepọ̀ tí ó dán mọ́rán wà láàárín àwọn ọmọ ènìyàn Pẹ̀lú gbogbo oriki tí àwọn onímọ̀ ti fún èdè a lè sọ pé èdè ni ohùn tí ó ní ètò àti ìtumọ̀ tí a sì fi ìró èdè gbé jáde Àwọn ìró èdè Yorùbá bí àpẹẹrẹ ni ìró fáwẹ́lì ìró ohùn àti ìró kọ́ńsónáǹtì Àwùjọ tàbí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ló ní èdè tirẹ̀ Ìdí niyi tí a fi máa ń sọ pé èdè Yorùbá èdè Ìgbò èdè Hausa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Síwájú sí i ohùn tí a bá pè ní èdè gbọdọ̀ jẹ́ ohùn tí a fi ìró èdè gbé jáde Ìró yìí ni a lè pè ní ariwo tí a fi ẹnu pa Èdè nílò kí á kọ́ ọ fún ìgbà pípẹ́ díẹ̀ kí ènìyàn tó lo lè sọ ọ́ Èyí ti di bárakú tàbí àṣà fún wa pé a gbọdọ̀ kọ́ ọmọ tí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ní èdè Àkíyèsí àti ìwádìí yìí ni àwọn elédè Gẹ̀ẹ́sì ń tọ́ka sí nígbà tí wọ́n bá sọ pé Ọmọ tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí tí a kò kọ́ ní èdè tí ó sì ń gbé láàárín ẹranko kò lè sọ èdè Nítorí náà èdè àti àwùjọ jẹ́ kòríkòsùn Bákan náà gbogbo èdè kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ìró èdè tirẹ̀ tí à ń pè ní fóníìmù Bí a bá mú fóníìmù yìí lọ́kọ̀ọ̀kan kì í dá ìtumọ̀ ní Ìgbà tí a bá kàn àwọn fóníìmù pọ̀ mọ́ ara wọn gẹ́gẹ́ bí òfin èdè tó ń lo fóníìmù bẹ́ẹ̀ ló tó lè ní ìtumọ̀ Bí àpẹẹrẹ; Kó yàtọ̀ sí kú Kí yàtọ̀ sí ké Kọ́ yàtọ̀ sí ká Kún yàtọ̀ sí kú Kán yàtọ̀ sí ká Kì í ṣe gbogbo ìró fáwẹ́lì ni fóníìmù Àwọn fáwẹ́lì an àti ọn jẹ́ ẹ̀dà fóníìmù nítorí pé lẹ́yìn kọ́ńsónáǹtì tí a máa ń lo ètè ní pípè rẹ̀ àti wà ni a ti máa ń lo ìró ọn tí a sì máa ń lo ìró an lẹ́yìn àwọn kọ́ńsónáǹtì t ó kù Nítorí èyí kò lè sí ìfọ́nká aṣèyàtọ̀ ọn àti an Bí àpẹẹrẹ; Ọgbọ́n kò sí *ọgbán ọdán Kódà ní ìṣọwọ́sọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá mìíràn ìró ọn ni ó wà fún ọ̀rọ̀ méjèèjì Ẹ̀KAÈDÈ Ní òde òní orúkọ àjùmọ̀jẹ́ tí àwọn ọmọ káàárọ̀oòjíire ń pe ara wọn àti èdè wọn ni Yorùbá Ṣùgbọ́n báyìí kọ́ ni ọ̀rọ̀ rí ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àdúgbò kan tàbí ẹkùn kan ló ní orúkọ ti ara rẹ̀ àti èdè ní àpapọ̀ tí kò sì sí orúkọ kan pàtó fún ẹ̀yà yìí ní aye ìgbà náà Irú àwọn orúkọ tí a lè rí tí wọ́n fi ń pé ẹ̀yà Yorùbá ni Akú Lúkúmù Ọ̀yọ́ Ìṣẹ́kìrí èyí tí ó wà ní ìpínlẹ̀ lónìí Ọ̀wọ̀ Ẹ̀gbá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ó ní orúkọ kan tí wọ́n ń pe àwọn aládùúgbò tàbí alábàágbé àwọn ẹ̀yà èdè Yorùbá tí wọ́n ń sọ ní orileèdè Togo àti Bini èyí tí a mọ̀ sí Ànàgó kódà orúkọ náà ṣì wà títí di òní ní àdúgbò kan gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́ Lúkúmù jẹ́ orúkọ tí ẹ̀yà èdè Yorùbá tí wọ́n kó lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ Amẹ́ríkà fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀ Àwọn ti Gúúsù àti Àríwá a máa pe ara wọn ní ará olùkù mi tí ó sì túmọ̀ sí ọ̀rẹ́ mi ní aye ìgbà náà Àwọn onímọ̀ fúnra wọn pé láti ara ilẹ̀ Àkókó bí; Ìkàrẹ̀ àti Ọ̀kà ni orúkọ yìí Lúkúmù ti jáde wá Akú ni a gbàgbọ́ pé ó jẹ jáde láti ara ìkíni ẹ kú tàbí ọ kú a kú ni orúkọ tí àwọn ilẹ̀ Saró fún ẹ̀yà Yorùbá tí wọ́n jẹ́ ẹrú ti wọ́n sì fún ní òmìnira ní ilẹ̀ Saró ní àkókò náà Gẹ́gẹ́ bí Awóbùlúyì ṣe sọ Ó ní a lè pín àwọn ẹ̀yà Yorùbá tí a dárúkọ sí ọ̀nà méjì Ó ní àwọn kan jẹ́ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó kàn jẹ́ wí pé wọ́n bá èdè Yorùbá tan lásán ni Irú àwọn èdè bẹ́ẹ̀ ni Ànàgó Ìgàlà Òkèàgbè Bini Iṣẹ́kìrí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ìgbàgbọ́ àwọn onímọ̀ ni pé orírun kan náà ni àwọn èdè ní Wọ́n sì tún sọ pé èdè ọmọ ènìyàn kò lè ṣe kí ó máa yí padà Àwọn nǹkan bí ogun tàbí àjàkálẹ̀ àrùn ni ó ṣe okùnfà oríṣìíríṣìí ẹ̀kaèdè ní àkókò yìí tí àwọn èdè ní àtijọ́ sì túká ní aye ìgbà náà Ó tẹ̀síwájú pé àjàkálẹ̀ àrùn yìí tàbí ogun ló fa kí àjọṣepọ̀ máse déédé mọ́ láàárín wọn tí eléyìí sì mu ìyàtọ̀ wà nínú àwọn èdè náà lónìí A rí àwọn tí ó yàtọ̀ sí èdè Yorùbá òde òní bí èdè Bini èdè Òkèàgbè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Àwọn ni ẹ̀kaèdè àtijọ́ tí ó kọ́ yapa kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó kù Ó sì jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé ẹni tí kò bá gbọ́ ju Yorùbá Ọ̀yọ́ tàbí Ìbàdàn lọ kò lè gbọ́ èdè tí àwọn wọ̀nyí ń sọ Ó ya àwòrán bí ó ti lérò pé àwọn èdè yìí ṣe tan mọ́ ara wọn láyé àtijọ́ ó lo àwòrán yìí láti ṣe àfihàn ìsọ̀rí tí a pín èdè yìí sí ÈDÈ AṢORÍRUN Awóbùlúyì Èdè Aṣorírun Èdè Yorùbá Ó tún mẹ́núba pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èdè Yorùbá yìí tí yípadà Awóbùlúyì tún ṣe àpẹẹrẹ pẹ̀lú àwọn ẹyọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti fi ìyàtọ̀ hàn lórí àwọn èdè tí a ti dárúkọ sáájú Awóbùlúyì Yorùbá Ànàgó Ìgàlà Ìṣẹ́kìrì Òkèàgbè Ìgbò Bìní ọwọ́ ọwọ́ ọwọ́ ọwọ́ úwọ́ aka òbọ́ Ojú ojú íjù ójú ányá àrọ́ Ó sọ pé àwọn tí ó yàtọ̀ sí ti èdè Yorùbá jù ni òde òní ni Òkèàgbè èdè Ìgbò èdè Bìní àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ní báyìí a ó fi àwọn èdè tí a ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ sáájú pé wọ́n jẹ́ èdè Yorùbá òde òní ṣe àpẹẹrẹ ìyàtọ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá Èyí ni àpẹẹrẹ bí a ṣe ń pe àwọn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ní ìṣọ̀rí ẹ̀yà Yorùbá tí a ní ni òdeòní Bákan náà Awóbùlúyì tún fi àwọn gbólóhùn yìí ṣe àpẹẹrẹ láàárín Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Òkèàgbè Ìgbómìnà Ìkálẹ̀ àti Oǹdó Adéfilá YORÙBÁ ÒKÈÀGBÈ ÌKÁLẸ̀ ÌGBÓMÌNÀ Oǹdó YORÙBÁ ÒKÈÀGBÈ ÌGBÓMÌNÀ lílù ni mo lù ú A gbàgbọ́ pé àwọn tó ń sọ àwọn ẹ̀kaèdè tí a ti mẹ́núba ṣáájú mọ̀ pé ẹ̀yà kan náà ni àwọn bí ó tile jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́ lẹ́nu yàtọ̀ sí ara wọn ṣùgbọ́n síbẹ̀ kò sí orúkọ àjùmọ̀jẹ́ kan pàtó tí à ń pe àwọn ẹ̀kaèdè wọ̀nyí yàtọ̀ sí Yorùbá tí gbogbo ènìyàn ti mọ̀ wọ́n sí Nínú ìtàn mìíràn tí a kà nípa ijọbá Ọ̀yọ́ ayé àtijọ́ ni wọ́n ti fi ìgbà kan pè ni Yorùbá tí àwọn Ìjẹ̀bú àti àwọn Ìyàgbà kì í sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pe àwọn ní ẹ̀yà Yorùbá Àwọn ẹ̀yà Ọ̀yọ́ àti Ìbàdàn ni wọ́n kà kún Yorùbá Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀rọ̀ rí láàárín àwọn Ẹ̀gbá ayé àtijọ́ Èyí fi hàn pé gbogbo àwọn ẹ̀yà yìí kọ́ ló gbà pé Yorùbá ni àwọn ní ìgbà náà ṣùgbọ́n lákòókò yìí ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá gbogbo wọn ló ti faramọ́ pé ọmọ Yorùbá ni àwọn ń ṣe Ẹ̀YÀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ Ìtàn fi yé wa pé ẹ̀yà Ìgbómìnà jẹ́ ara ọmọ Odùduwà Ọ̀ràngún IléÌlá sì ni ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ náà dó ÌláỌ̀ràngún sì ni olúìlú fún ẹ̀yà Ìgbómìnà gbogbo tí ó sì jẹ́ pé àwọn ìlú tó wà ní abẹ́ ẹ̀yà yìí ló ní ọba fún ara wọn Àmọ́ sá gbogbo wọn ló gbà pé ÌláỌ̀ràngún ni olúìlú fún àwọn Àjọṣepọ̀ tó nípọn wà láàárín àwọn ìlú wọ̀nyí A rí ètò ọrọ̀ajé àti àjọṣepọ̀ okoòwò tó pa gbogbo àwọn ìlú wọ̀nyí pọ̀ Ọba ÌláỌ̀ràngún ló jẹ́ olórí fún gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Ìgbómìnà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú ìtàn nígbà kan Oríṣìíríṣìí ìlú ló parapọ̀ tí wọ́n sì wá di ẹ̀yà Ìgbómìnà A rí àwọn ìlú bí i; Ìgbàjà ÒmùÀrán Òmùpo Ọ̀raÌgbómìnà Àrándùn ÒròÀgọ́ Ọ̀là Àjàṣẹ́Ìpo Òró Ìdọ̀fìàn Ṣàárẹ́ Rorẹ́ ÀránỌ̀rin Iwó ÌpetùÌgbómìnà Èdìdi ÒkèOnígbìnín ÌsánlúÌsin Òkò ÌjáráÌsin ÒwùÌsin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú ìtàn lábẹ́ àkóso kan ṣoṣo ni gbogbo àwọn ìlú wọ̀nyí wà tẹ́lẹ̀ kí ó tó di pé ogun Ìlọrin tú wọn ká tí àwọn mìíràn sì bọ̀ sí abẹ́ ìjẹgàbalé àwọn Ìlọrin Adéfilá a lè pin ẹ̀yà Ìgbómìnà sí ìṣọ̀rí mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nítorí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wọn ní orúkọ àjùmọ̀jẹ́ kan náà síbẹ̀ ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ sì wà nínú àwọn ìlú wọ̀nyí bí Adéfilá ṣe pín in sísọ̀rí nìyí; Ìṣọ̀rí I Ìgbómìnà mọ̀ọ́n yẹ̀ ÒròÀgọ́ Ọ̀là ỌwáKájọlà Òkò OkeÒrò Ọyátẹ̀dó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ìṣọ̀rí II Ìgbómìnà mo sànÀjàṣẹ́Ìpo Ìgbàjà Ẹkùn mẹ́sànán Òró Ìdọ̀fìàn Àgbámú Àrándùn ÌpetùÌgbómìnà Òmùpo Ganmọ Sanmọra Agbọndà Ṣàárẹ́ Owódé Omido Rorẹ́ Ìjanọ̀tùn Àgbélé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ìṣọ̀rí III Ìgbómìnà isin ÌsánlúÌsin ÌjáráÌsin Iwó Ẹlẹ́yìn Èdìdi ÒwùÌsin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ìṣọ̀rí Ìgbómìnà Ìlá ÌláỌ̀ràngún ÒkèÌlá Ọ̀ràÌgbómìnà Nínú àwọn ìṣọ̀rí tí a pín àwọn ẹ̀yà Ìgbómìnà yìí sí a rí àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ nínú èdè wọn A kò lè sọ pàtó ohùn tí ó fa eléyìí ṣùgbọ́n a lérò pé èyí wáyé latari ìjẹgàba lé àwọn Ìlọrin tí ó sì jẹ́ kí èdè wọn ma farahàn nínú ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà kan pàápàá àwọn ìlú tó súnmọ́ Ìlọrin A lè rí àwọn àpẹẹrẹ nínú àwọn ìlú bí i Ganmọ Àmáyọ̀ tí a sí rí ẹ̀kaèdè Ìlọrin tó tí dàpọ̀ mọ́ ẹ̀ka Ìgbómìnà ní àwọn ìlú wọ̀nyí ÌṢẸ̀DÁ Ọ̀RỌ̀ MỌFỌ́LỌ́JÌ Ọ̀pọ́ onímọ̀ ló ti ṣiṣẹ́ lórí bí a ṣé ń ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ nínú èdè èyí tí í ṣe mọfọ́lọ́jì Lára àwọn onímọ̀ tí o fún mọfọ́lọ́jì ní oriki ni a ti rí Awóbùlúyì ó ní Àwọn ọ̀nà gbogbo tí a gbà ṣẹ̀dá àwọn ẹyọ ọ̀rọ̀ inú èdè kọ̀ọ̀kan àti onírúurú wúnrẹ̀n tí a lò fi ṣe bẹ́ẹ̀ Tinuoye kí mọfọ́lọ́jì báyìí Mọfọ́lọ́jì níṣe pẹ̀lú bí a ṣe ń to mọ́fíìmù pọ̀ láti di ọ̀rọ̀ Taiwo kí mọfọ́lọ́jì báyìí Mọfọ́lọ́jì ni ẹ̀ka gírámà tí a ti máa ń kọ́ nípa ìhun ọ̀rọ̀ Olúnládé náà kí mọfọ́lọ́jì báyìí Ẹ̀kọ́ nípa mọ́fíìmù àti òfin tí ó de ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ nínú èdè ni mọfọ́lọ́jì Pẹ̀lú oriki tí àwọn onímọ̀ fún mọfọ́lọ́jì a rí i wí pé mọfọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa bí a ṣe ń ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ nínú èdè Nínú èdè Yorùbá mọ́fíìmù méjì ló wà Mọ́fíìmù sì ni à ń pé àwọn wúnrẹ̀n tí a rí tí ó para pọ̀ ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tàbí àwọn tí a fúnra wa ṣín pọ̀ fi ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ mọ́fíìmù ni {a} mọ́fíìmù ni {lọ} náà nínú àlọ tí ó jẹ́ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan nínú èdè Yorùbá Ami mọ́fíìmù ni { } àkámọ́ onídodo Awóbùlúyì ó ní oríṣìí mọ́fíìmù méjì tí ó wà ni mọ́fíìmùadádúró àti mọ́fíìmùafarahẹ Mọ́fíìmùadádúró ni àwọn mọ́fíìmù tí wọn lè dá dúró gẹ́gẹ́ bí ẹyọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n sí ní ìtumọ̀ Àpẹẹrẹ iru àwọn mọ́fíìmù báyìí nínú èdè Yorùbá ni { wá lọ dé fò} àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Àwọn mọ́fíìmù afarahẹ ni àwọn mọ́fíìmù tí kò lè dá dúró kí wọ́n ní ìtumọ̀ Èyí ni pé wọn kì í ṣe ẹyọ ọ̀rọ̀ kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n máa ń fi ara hẹ sí egbe mọ́fíìmù adádúró ni Iṣẹ́ àfòmọ́ ni wọ́n ń ṣe nínú gírámà Àpẹẹrẹ iru mọ́fíìmù bẹ́ẹ̀ ni {à} nínú àlọ àti { ẹ̀ } nínú ẹ̀ṣẹ̀ ÀWỌN MỌ́FÍÌMÙ ÀFARAHẸ Oríṣìí àfòmọ́ tàbí mọ́fíìmùàfarahẹ méjì ni a ṣábà máa ń kàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ inú èdè Yorùbá Ọ̀kan nínú wọn àfòmọ́wájú àfòmọ́wájú èyí tí a máa ń ta mọ́ ìbẹ̀rẹ̀ tàbí iwájú wúnrẹ̀n mìíràn èkejì àfòmọ́àsopọ́ èyí tí ó máa ń sọ wúnrẹ̀n méjì pọ́ Àfòmọ́wájú pé oríṣìí méjì bákan náà Àwọn kan jẹ́ fáwẹ́lìàfòmọ́wájú ajẹ́fáwẹ́lì aṣefáwẹ́lì àwọn kan sì jẹ́ kọ́ńsónáǹtìàfòmọ́wájú ajẹkọ́ńsónáǹtì aṣe kọ́ńsónáǹtì ÀFÒMỌ́WÁJÚ AṢEFÁWẸ́LÌ Bí a bá yọ u àti àwọn fáwẹ́lì àrànmúpè sílẹ̀ gbogbo fáwẹ́lì yooku nínú èdè Yorùbá ni ó máa ń ṣiṣẹ́ àfòmọ́wájú aṣefáwẹ́lì Àwọn wúnrẹ̀n tí iru àfòmọ́ yìí sábà máa ń ta mọ́ lára lè jẹ́ ọ̀rọ̀ìṣe àpólàìṣe ọ̀rọ̀orúkọ tàbí àpọ́nlé Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ i Àfòmọ́wájú àti ọ̀rọ̀ìṣe à lọ alọ à bọ̀ àbọ̀ ì ṣe ìṣe ò kú òkú ẹ̀ kó ẹ̀kọ́ ọ̀ rẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ gé ègé ẹ̀ ṣe èṣe Àfòmọ́wájú àti àpólàìṣe ọ̀rọ̀ìṣe pẹ̀lú àbọ̀ rẹ̀ a dájọ́ adájọ́ ọ̀ dalẹ̀ ọ̀dàlẹ̀ ò kóbó òkóbó o ní owó olówó o ni ilẹ̀ ònilẹ̀ o ni ẹgẹ ẹlẹgẹ́ iii Àfòmọ́wájú àti ọ̀rọ̀orúkọ è kíkániná èékánná a dídùn àádùn ọ̀ lẹ̀lẹ̀ ọ̀lẹ̀lẹ̀ọ̀ọ̀lẹ̀ ọ̀ pẹ́lẹ́ngẹ́ ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́ ò títọ́ òtítọ́ è bíbú èébú ọ̀ dẹ̀dẹ̀ ọ̀dẹ̀dẹ̀ a yẹyẹ ayẹyẹ Àfòmọ́wájú àti Àpọ́nlé à kókó àkókò à tìlọ àtìlọ à ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ àṣẹ̀ṣẹ̀yọ à dédé àdédé a ti àárọ̀ àtàárọ̀ à kúkú ì bí àkúkkúùbí ÀWỌN MỌ́FÍÌMÙ ADÁDÚRÓ Gẹ́gẹ́ bí a tí wí tẹ́lẹ̀ àwọn mọ́fíìmù tí ó dá dúró gẹ́gẹ́ bí ẹyọ ọ̀rọ̀ ni à ń pé ní mọ́fíìmùadádúró Irú àwọn mọ́fíìmù báyìí ni ó pọ̀ jù nínú èdè Yorùbá Bá yìí náà nì ó máa ń rí nínú àwọn èdè ọmọnìyàn yòókù Àpẹẹrẹ wọn ni gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ìṣe ònísílébùkan bí dé sá fò jẹ sin ró rọ́ rọ̀ rẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni èdè Yorùbá Àwọn kan nínú àwọn mọ́fíìmùadádúró tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀orúkọ a máa ní ẹ̀dà méjì méjì dípò ẹyọ ẹ̀dá kan ṣoṣo Ẹ̀dàòde àti ẹ̀dáabẹ́nú ni a mọ iru àwọn ẹ̀dà bẹ́ẹ̀ sí Fáwẹ́lì i aláfìbọ̀ ni o máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ́ ẹ̀dàabẹ́nú Bí àpẹẹrẹ Ẹ̀dàòde Ẹ̀dàabẹ́nú yàrá iyàrá yanrìn iyanrìn gbèsè igbèsè bùsùn ìbùsùn lẹ̀kùn ilẹ̀kùn bojì ibojì balùwẹ̀ ibalùwẹ̀ káà ikáà pélé ipélé wèrè iwèrè kọ̀rọ̀ ikọ̀rọ̀ wèrèpè iwèrèpè yàrà iyàrà wárápá iwárápá bàdí ìbàdí báarú ìbaárú karahun ìkarahun Òfin ìpàrójẹ kì í pa fáwẹ́lì i aláfibọ̀ ti ìbẹ̀rẹ̀ iwèrè àti igbèsè jẹ nínú a ṣe iwèrè aṣiwèrè aṣièrè a jẹ igbèsè ajigbèsè ÀWỌN Ọ̀NÀ ÀGBÀ ṢẸ̀DÁ Ọ̀RỌ̀ Àyẹ̀wò àfarabalẹ̀ ṣe fi hàn pé oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni a gbà ṣẹ̀dá ọ̀pọ́ ọ̀rọ̀ nínú èdè Yorùbá pàápàá àwọn ọ̀rọ̀orúkọ ẹ̀yán ọ̀rọ̀iṣẹ́ àti àpọ́nlé Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ti à ń gbà ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ni a fẹ́ gbéyẹ̀wò nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ÌṢẸ̀DÁ Ọ̀RỌ̀ ORÚKỌ Gbogbo ọ̀rọ̀ tó bá jẹ́ orí nínú àpólà ọ̀rọ̀orúkọ ni ọ̀rọ̀orúkọ Ọ̀rọ̀orúkọ máa ń ṣiṣẹ́ olùwà fún gbólóhùn àbọ́ fún ọ̀rọ̀ìṣe tàbí àbọ́ fún ọ̀rọ̀atọ́kùn Pẹ̀lúpẹ̀lú ó máa ń ṣiṣẹ́ ẹ̀yán a sì máa yán ọ̀rọ̀orúkọ Ọ̀rọ̀orúkọ ìpìlẹ̀ tí a kọ́ ṣẹ̀dá wà Bí àpẹẹrẹ ayé ilẹ̀ owó aya ọba ọ̀rọ̀orúkọ tí a ṣẹ̀dá wà Bí àpẹẹrẹ ìṣẹ́tí oníṣu agọ̀ àìmò òǹtẹ̀ olùse Àwọn ìgbésẹ̀ fún ìsọdorúkọ ni lílo àfòmọ́ lílo àpètúnpè kíkan ọ̀rọ̀ pọ̀ àti ọ̀rọ̀ àyálò ORÍ KẸTA FONỌ́LỌ́JÌ ÈDÈ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ SÍ Ẹ̀KAÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ ÌFÁÀRÀ Nínú orí yìí ni á ti gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ lórí fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà A ṣe àyẹ̀wò àwọn ìró tí a lè bá pàdé nínú ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà ìyẹn ìró kọ́ńsónáǹtì ìró fáwẹ́lì àti ìró ohùn A gbìyànjú láti ṣe àpèjúwe bí a ṣe ń pè wọ́n pẹ̀lú Àwọn ìró tí wọn jẹyọ nínú èdè méjèèjì náà ni a tún ṣe àkàwé wọn nínú orí yìí bákan náà FONỌ́LỌ́JÌ Ẹ̀KAÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ Ọ̀pọ́ onímọ̀ ni wọ́n ti ṣiṣẹ́ lórí fonọ́lọ́jì Lára wọn ni a ti rí Ó fún fonọ́lọ́jì ní oriki báyìí Fonọ́lọ́jì ni ètò àti bátànì ìró tí ó máa ń farahàn nínú èdè Bákan náà a rí Ó ní Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀ka lìńgúísììkì tí ó máa ń gbájúmọ́ ètò àti bátànì ìróifọ̀ Olunlade kí fonọ́lọ́jì Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ tí a tì máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró nínú èdè kan pàtó Oyebade náà kò gbẹ́yìn; ó ní Fonọ́lọ́jì ni ìmọ̀ tí ó gbájúmọ́ ìró ajẹmohùn tí a máa ń rí nínú afọ̀ ọmọnìyàn àti bátànì tí àrokò yìí ń gbà gbé afọ̀ tí ó ni ìtumọ̀ jáde Pẹ̀lú oriki tí àwọn onímọ̀ fún fonọ́lọ́jì a rí wí pé fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá ìró nínú èdè kan pàtó ÈTÒ ÌRÓ NÍ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ Ètò ìró tí a lè bá pàdé ní ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà nì ìró kọ́ńṣónáǹtì ìró fáwẹ́lì àti ìró ohùn Ìró kọ́ńṣónáǹtì mẹ́tàdínlógún ni a lè bá pàdé nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà bí o ti rí ní Yorùbá àjùmọ̀lò Àwọn ni wọ̀nyí Ìró fáwẹ́lì àìránmúpè méje àti ìró fáwẹ́lì àrànmúpè márùnún ni ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà a e ẹ i o ọ u àti an ọn in ẹn un A ni ìró ohùn òkè ìró ohùn àárín àti ìró ohùn ìsàlẹ̀ ÌRÓ KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ NI Ẹ̀KAÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ Ohun tí a o yẹ̀wò níbí yìí ni àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì tí a lè rí nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà Gẹ́gẹ́ bí oríkì tí Bámgbóṣé fún kọ́ńsónáǹtì Ó ní ìró kọ́ńsónáǹtì ni èyí tí ìdíwọ́ máa ń wà ní jíjáde èémí ní káà ẹnu Tí a bá wo oríkì yìí a o rí pé bí ó ṣe wà nínú olórí ẹ̀ka èdè èyí tíí ṣe Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni a ṣe rí nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà nítorí pé gbogbo kọ́ńsónáǹtì inú èdè ni a máa ń pé nígbà tí ìdíwọ́ bá wà fún èémí Àtẹ ìsàlẹ̀ yìí yóò tún ṣàlàyé ní kíkún àwọn ibi ìsẹnupè àti ọ̀nà ìsẹnupè wọn IBI ÌSẸNUPÈ Ọ̀NÀ ÌṢẸNUPÈ Afètèpè Àfeyínfètèpè Afèrìgìpè Afàjàafèrìgìpè Afàjàpè Afafàsépè Afafàsétèpè Àfitánánná pè Àṣẹ́nupè b t d k g gb Àfúnnupè f s h Àsèsì Àránmúpè m n Àréhọ́n r Afègbénupè l Àsèésétán j w àṣénupè afètèpè akùnyùn ÌSÚYỌ NI ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ bata bàtà babalawo babaláwo baba bàbá bi bì bo bò ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ọba obi obì aburo àbúrò baba bàbá t àṣénupè afèrìgìpè àìkùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ tutu tutù tũtũ tuntun t tọ̀ ta tà tutu tútù ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ it itọ́ ìtã ìtàn ti ọtí ata ata rãti rántí àṣénupè afèrìgìpè akùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ dudu dúdú dùn de dé dúró dín ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ àádọ́ta yípadà ìdí pada padà àdán k àṣénupè àfàfàsépè àìkùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ kọ̀ǹkọ̀ koro kóró kọ̀nga kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ku kú ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ okùn aake àáké paki pákí iku ikùn okuku òkùnkùn àṣénupè afàfàsépè akùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ gígùn ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ igi igi ẹ̀gún ẹyin àgùntàn ogun àṣénupè àfàfàséfètèpè àìkùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ pẹ́pẹ́yẹ Pupa padà Pa pè ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ẹ̀pà epo apá àpò apẹ̀rẹ̀ gb àṣénupè àfàfàséfètèpè akùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ gbẹ́ gbà gbẹ́gi gbàgbé gbígbé ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ àgbọ̀n irungbọ̀n igbá ìgbín ìgbẹ́ àfúnupè afeyínfètèpè àìkùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ fo fò fẹ́ràn fa fà fọwọ́kàn fún ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ eefi èéfín ẹ̀fà afẹ́fẹ́ ekú àfúnupè afèrìgìpè àìkùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ sùn sáré sanwó sọ̀rọ̀ se sè ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ọsàn ẹsẹ̀ aṣọ iṣẹ́ isu iṣu afitánánnápè àfúnupè àìkùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ha wá híhun ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ Ìjàpá ahọ́n àsésí àfàjàfèrìgìpè akùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ Jó jókòó jí jù jẹun ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ Ojú Ẹja Òjò Ẹ̀jẹ̀ Ajá àrànmúpè afètèpè akùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ olóngbòméjìlá mẹ́rìnlá mọ̀ Mu mú ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ imu imú omi omi am amọ̀ m ọmọ ẹmu n àránmú afèrìgìpè akùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ nla ńlá na nà níbí nina nínà ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ inu inú ina iná ana àná ẹní konko koríko arẹ́họ́n afèrìgìpè akùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ rìn rántí Rà rẹ̀rín rán ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ eri orí ẹran irin ra ọ̀rá ara ara àfẹ̀gbẹ́ẹnupè afèrìgìpè akùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ aláǹgbá i lọ lu lù láìpé lu lu ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ìlèkùn ilẹ̀ ile ilé ila ilá alẹ́ àséèsétán àfàjàpè akùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ yìnyín jipada yípadà yan yàgbẹ́ ẹ̀fọn ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ijara iyàrá oyin aja aya ẹyẹ iyọ̀ àséèsétán afàfàséfètèpè akùnyùn ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ wuwo wúwo wọlé wiwa wíwá ÀÁRÍN Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ewúrẹ́ ìwọ ÌRÓ FÁWẸ́LÌ NÍ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú fáwẹ́lì èdè Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe wà nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà tí a bá ní kí á wo oríkì tí Bámgbóṣé fún fáwẹ́lì Ó sọ báyìí pé ìró fáwẹ́lì ni èyí tí èèmí máa ń jáde ni pípè rẹ̀ láì jẹ́ pé ìdíwọ́ kankan wà nínú káà ẹnu A rí nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú èdè Yorùbá àjùmọ̀lò pé bákan náà ni ìró fáwẹ́lì rí nínú àwọn méjèèjì Nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà oríṣìí ìró fáwẹ́lì méjì nì ó wà ìró fáwẹ́lì àìránmúpè àti ìró fáwẹ́lì àrànmúpè Àwọn ìró fáwẹ́lì àìránmúpè nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà ni wọ̀nyí a e ẹ i o ọ u nígbà tí a rí àwọn ìró fáwẹ́lì àrànmúpè wọ̀nyí an in ọn ẹn un Fún ìdí èyí a lè sọ pé kò sí ìyàtọ̀ láàárín ìró fáwẹ́lì Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà ATẸ FÁWẸ́LÌ ÀÌRÁNMÚPÈ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ iwájú àárín ẹ̀yìn Ohùn ìsàlẹ̀ àti àárín ìyẹn òkun kọ̀nga ìwọ ẹyin èje ÌGÚNLẸ̀ A rí wí pé kò sí ìyàtọ̀ nínú bí a ṣe ń pé ìró kọ́ńsónáǹtì àti ìró fáwẹ́lì inú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà tí a bá wò ó pẹ̀lú tí Yorùbá àjùmọ̀lò èyí tí i ṣe olórí ẹ̀ka èdè Bákan náà tí a bá wo àwọn ìró ohun tí a lè pàdé nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà a rí i pé kò yàtọ̀ sí ti Yorùbá àjùmọ̀lò ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe máa ń pé àwọn ọ̀rọ̀ wọn kọ̀ọ̀kan ni a ti rí ìyàtọ̀ ORÍ KẸ́RIN ÌṢẸ̀DÁ Ọ̀RỌ̀ORÚKỌ NÍ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ ÌFÁÀRÀ Oríṣìíríṣìí ni ìlànà àti ìgbésẹ̀ tí à ń gbà ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ èdè Yorùbá pín sí A o ṣe àfiwé ìgbésẹ̀ mọfọ́lọ́jì èdè Yorùbá àjùmọ̀lò pẹ̀lú ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà A rí i ní abẹ́ mọfọ́lọ́jì àwọn ìgbésẹ̀ àti ìlànà bí i lílo àpètúnpè kíkan ọ̀rọ̀ pọ́ lílo àfòmọ́ àti yíyá ọ̀rọ̀ láti inú èdè mìíràn bí Gẹ̀ẹ́sì Gbogbo àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí ló wà lábẹ́ mọfọ́lọ́jì ó sì sọ̀rọ̀ lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn pẹ̀lú àfiwé rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀kaèdè méjèèjì LÍLO ÀFÒMỌ́ À ń fi àfòmọ́ ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ titun nípa kíkan mọ́fíìmù pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ìṣe tàbí ọ̀rọ̀orúkọ Oríṣìí ìlò àfòmọ́ méjì tó wà ni ìlò àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àti ìlò àfòmọ́ àárín Àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ Fáwẹ́lì Ọ̀rọ̀ìṣe ẹ̀kaÌgbómìnà Àsọdorúkọ Ẹ̀ka Ìgbómìnà Yorùbá Àjùmọ̀lò ọ de ọdẹ ọdẹ à bọ̀' àbọ̀ àbọ̀ ẹ bí ẹbí ẹbí e gbé egbé egbé ẹ̀ bẹ̀ ẹ̀bẹ̀ ẹ̀bẹ̀ ọ̀ dẹ̀ ọ̀dẹ̀ ọ̀dẹ̀ Àpólàìṣe Àsọdorúkọ Fáwẹ́lì Àpólàìṣe ẹ̀ka Ìgbómìnà Àsọdorúkọ Ẹ̀ka Ìgbómìnà Yorùbá Àjùmọ̀lò ì dí òwọ́ ìdíwọ́ ìdíwọ́ a wa ọkọ̀ awakọ̀ awakọ̀ ọ mu ọtín òmùtín òmùtí ò jẹ owú òjòwú òjòwú à ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ àsẹ̀sẹ̀yọ àṣẹ̀ṣẹ̀yọ à tètè dé àtètèdé àtètèdé olù Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ olù ṣe olùse olùṣe olù kọ́ olùkọ́ olùkọ́ olù wọ̀ olùwọ̀ olùwọ̀ olù gbìn olùgbìn olùgbìn olù sè olùsè olùsè olù yà olùyà olùyà àì Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ àì lọ àítì lọ kòítìlọ àìlọ àì kú àìkú àìkú àì sùn àìsùn àìsùn àì jẹ àìjẹ àìjẹ àì mu àìmu àìmu òǹ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ òǹ tẹ̀ òǹtẹ òǹtẹ òǹ kọ wé ìkọ̀wé òǹkọ òǹ kà òǹka òǹkà òǹ gbẹ òǹgbẹ òǹgbẹ o ní Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ o ní iṣẹ́ oníṣẹ́ oníṣẹ́ o ní gèlè óńgèlè onígèlè o ní owó olówó olówó o ní ẹran ẹlẹ́ran ẹlẹ́ran à ti Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ à ti há àtihá àtiwá à ti sùn àtisùn àtisùn à ti dé àtidé àtidé à ti gbó àtigbọ́ àtigbọ́ ÀFÒMỌ́ ÀÁRÍN Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ kí ẹni kí ẹni ẹnikẹ́ni ẹnikẹ́ni ọkọ kí ọkọ ọkọkọ́kọ ọkọkọ́kọ ilé kí ilé iléèkílé ilékílé ọba kí ọba ọbaàkọ́ba ọbakọ́ba dé Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ìran dé ìran ìrandíran ìrandíran oko dé oko okodóko okodóko ọjọ́ dé ọjọ́ ọjọ́dọ́jọ́ ọjọ́dọ́jọ́ ìgbà dé ìgbà ìgbàdégbà ìgbàdégbà yí Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ilẹ̀yíilẹ̀ ilẹ̀sílẹ̀ ilẹ̀ẹ́lẹ̀ kò Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ojúkòojú ojúkojú ojúkojú rí Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ẹ̀míríẹ̀mí ẹ̀mírẹ̀mí ẹ̀mírẹ̀mí sí Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ìlú sí ìlú ìlúsìlú ìlúsílùú ilé sí ilé ilésílé ilésílé KÍKAN Ọ̀RỌ̀ PỌ̀ Àwọn ọ̀nà tí a máa ń gbà láti lo àkànpọ̀ ọ̀rọ̀ fi ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ni Ọ̀RỌ̀ORÚKỌ Ọ̀RỌ̀ORÚKỌ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÀFÒMỌ́ ÀPÓLÀÌṢE Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ a pa àlọ́ apàlọ́ apàlọ́ a gbé sí iwájú hàn gbésíwájú àgbésíwájú ṢÍṢE ÀPÈTÚNPÈ Oríṣìí àpètúnpè méjì ló wà Ìkíní ni àpètúnpè ẹlẹ́bẹ èkejì ni àpètúnpè kíkún ÀPÈTÚNPÈ ẸLẸ́BẸ À ń rí àpètúnpè ẹlẹ́bẹ nínú ìsọdorúkọ láti ara ọ̀rọ̀ìṣe àti sísọ ọ̀rọ̀ìṣe di ọ̀rọ̀àpèjúwe láti ṣe ìsọdorúkọ a óò ṣe àpètúnpè kọ́ńsónáǹtì àkọ́kọ́ a óò sì ti fáwẹ́lì i olóhùnòkè kún un Bí àpẹẹrẹ ÀPÈTÚNPÈ ẸLẸ́BẸ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ Há Bí i ti òkè yìí náà ni síso ọ̀rọ̀ìṣe di ọ̀rọ̀àpèjúwe Ìyàtọ̀ tó wà ni pé fáwẹ́lì u lè gba ipò fáwẹ́lì i nínú àwọn ọ̀rọ̀àpèjúwe kan Bí àpẹẹrẹ ÀPÈTÚNPÈ ẸLẸ́BẸ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÀPÈTÚNPÈ KÍKÚN Ọ̀rọ̀ orúkọ Ọ̀rọ̀ orúkọ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÀpólàÌṣe Àpólà Ìṣe Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÀFÒMỌ́ ÀÁRÍN OR Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ Ọ̀RỌ̀ ÀYÁLÒ À ń yá ọ̀rọ̀ lò láti inú àwọn èdè tí Yorùbá ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àpẹẹrẹ àwọn èdè bẹ́ẹ̀ ni Gẹ̀ẹ́sì Faransé Lárúbáwá Haúsá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Láti inú èdè Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ èdè àjùmọ̀lò ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà a máa ń yá ọ̀rọ̀ lò ní ọ̀nà wọ̀nyí; FÍFIFÁWẸ́LÌRỌ́PÒ ARA WỌN GẸ̀Ẹ́SÌ Ẹ̀KA ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ páànù páànù rọ́bà rọ́bà Náànsì Nọ́ọ̀sì FÍFIKỌ́ŃSÓNÁǸTÌRỌ́PÒARAWỌN GẸ̀Ẹ́SÌ Ẹ̀KAÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ pálọ̀ pálọ̀ sọ́ọ̀sì ṣọ́ọ̀ṣì FÍFI FÁWẸ́LÌ PARÍ Ọ̀RỌ̀ TÍ KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ PARÍ GẸ̀Ẹ́SÌ Ẹ̀KAÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ sọ́ọ̀bù ṣọ́ọ̀bù fọ́ọ̀kù fọ́ọ̀kù féèlì féèlì PÍPÍN ÌṢÙPỌ̀ KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ NÍYÀ GẸ̀Ẹ́SÌ Ẹ̀KAÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ Dọ́kítà Dọ́kítì síléètì síléètì búrẹ́dì búrẹ́dì mílíìkì mílíìkì LÍLO FÁWẸ́LÌ ÀRÁNMÚPÈ GẸ̀Ẹ́SÌ Ẹ̀KAÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ karosínìnnì kẹrosínìnnì Ọ̀rọ̀ tí bàtánì sílébù rẹ̀ bá jẹ́ K F K yóò di K F F K F nínú èdè Yorùbá Bí àpẹẹrẹ; GẸ̀Ẹ́SÌ Ẹ̀KAÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ páànù páànù kọ́ọ̀bù kọ́ọ̀bù Àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tí a yá lò ní tẹ̀léńtẹ̀lé ohùn okè àti ti ìsàlẹ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ Ẹ̀KAÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ tí ì tí ì wáyà wáyà kọ̀lá kólá sọ́jà sójà bébà bébà Fáwẹ́lì olóhùnòkè lè bẹ̀rẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ àyálò mìíràn Bí àpẹẹrẹ; GẸ̀Ẹ́SÌ Ẹ̀KAÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ọ́fíìsì ófíìsì ásììdì ásíìdì ẹ́njíìnì ẹ́ńjíìnì álọ́ọ̀mù álọ́ọ̀mù áńkọ́ọ̀bù áńkọ́ọ̀bù ẹ́mbúlòòkù ẹ́ńfílóòpù Ọ̀rọ̀àyálò mìíràn wà tó jẹ́ pé bí fáwẹ́lì inú wọn ṣe jẹyọ lòdì sí jíjẹyọpọ̀ fáwẹ́lì nínú èdè Yorùbá Àpẹẹrẹ ni GẸ̀Ẹ́SÌ Ẹ̀KAÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ bébà bébà télọ̀ télọ̀ mọ́ńtọ̀ mọ́tò fọ́tò fọ́tò Ìlànà méjì ni a fi máa ń yá ọ̀rọ̀ lòìlànà àfetíyá àti àfojúyá bí ó ṣe rí ní Yorùbá àjùmọ̀lò àfetíyá ni bí a ṣe gbọ́ ọ tí wọ́n sọ ó lẹ́nu Àfojúyá ni bí a ṣe rí i tí wọn kọ ó sílẹ̀ Bí àpẹẹrẹ GẸ̀Ẹ́SÌ Ẹ̀KAÌGBÓMÌNÀ Àfetíyá Báíbùlù tébùrù Pítà Ésítà GẸ̀Ẹ́SÌ Ẹ̀KAÌGBÓMÌNÀ Àfojúyá Bíbélì tábìlì Pétérù ÉsítéríEésítà Àwọn ọ̀rọ̀ tí a yá láti inú èdè Lárúbáwá LÁRÚBÁWÁ Ẹ̀KAÌGBÓMÌNÀ Gèfèrí àdúà wòlíì Àwọn ọ̀rọ̀ tí a yá láti inú èdè Hausa HAUSA Ẹ̀KAÌGBÓMÌNÀ àlááfíà àlùbáríkà àlùbọ́sà ÌGÚNLẸ̀ A rí wí pé kò sí ìyàtọ̀ nínú bí a ṣe ń pé ìró kọ́ńsónáǹtì àti ìró fáwẹ́lì inú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà tí a bá wò ó pẹ̀lú ti Yorùbá àjùmọ̀lò èyí tí í ṣe olórí ẹ̀ka èdè Bákan náà ìró ohùn ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà kò yàtọ̀ sí ti Yorùbá àjùmọ̀lò ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe máa ń pé àwọn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ni a ti rí ìyàtọ̀ Bí àpẹẹrẹ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ọsẹ̀ ẹsẹ̀ erí orí ó mú yìn mí fihàn sọ̀nràn sọ̀rọ̀ sié ṣeré nǹkúnun nǹkan po pa È dáa kò dára Kékeé kékeré ẹ̀gin ẹ̀yìn ahun ìjàpá òsè òsì há wá súré sáré Àhọn ọmọ àwọn ọmọ Láǹdè aláǹgbá Àhíyá ọ̀bọ Ìyẹ́ǹyé ìyẹ́ Músù Olóńgbò Esi ẹṣin Mọ̀ọ́nlù màálù Ohùn tí a tún rí tọ́ka sí ni wí pé ìró kọ́ńṣónáǹtì mẹ́tàdínlógún ni a lè bá pàdé nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà ṣùgbọ́n ni Yorùbá àjùmọ̀lò méjìdínlógún ni a lè bá pàdé Ní ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà kò sí ìró ∫ èyí sì wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò Bí àpẹẹrẹ Ẹ̀KAÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ isu iṣu isẹ́ iṣẹ́ asọ aṣọ sié ṣeré sisẹ ṣiṣẹ́ subu ṣubu ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ ÌFÁÀRÀ Gbogbo ilàkàkà wa lórí iṣẹ́ yìí àti àríwòye tí ó jẹyọ ni yóò jẹ́ pàtó orí yìí Bákan náà a o ṣe ìsọníṣókí àbájáde ìwádìí àmúyẹ àti ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ÌSỌNÍṢÓKÍ ÀBỌ́ ÌWÁDÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà àfiwé ìgbésẹ̀ mọfọ́lọ́jì ẹ̀dá èdè Ìgbómìnà sí Yorùbá àjùmọ̀lò ni ó dálé lórí Nínú orí mẹrin tí iṣẹ́ yìí dálé ni a ti gbìyànjú láti ṣe àlàyé ní kíkún ohùn tí mọfọ́lọ́jì jẹ́ fún wa Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ a ní mọfọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa mọ́fíìmù àti òfin tí ó de ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ nínú èdè Ṣùgbọ́n kí á tó sọ̀rọ̀ nípa mọfọ́lọ́jì a ti kọ̀ sọ ni ṣókí ìtàn tó rọ̀ mọ́ èdè Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà nítorí pé ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka èdè Yorùbá Bákan náà a tún gbéyẹ̀wò àwọn ìró tí o wa nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà ìyẹn ìró kọ́ńṣónáǹtì ìró fáwẹ́lì àti ìró ohùn A tún tiraka láti mu kí òǹkọ̀wé mọ oríṣìíríṣìí akitiyan tí àwọn onímọ̀ ti ṣe lórí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tí à ń pé ní mọfọ́lọ́jì Àyẹ̀wò àwọn ìgbésẹ̀ àti ìlànà mọfọ́lọ́jì kò gbẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí nítorí pé ìgbésẹ̀ àti ìlànà yìí ni mọfọ́lọ́jì dálé a sì ṣe àyẹ̀wò wọn ní fíníjíní pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ tí yóò fi jẹ́ kí ó yé òǹkàwé dáradára Ó sí tún dámi lójú pé àwọn àfiwé tí a ṣe nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà sí Yorùbá àjùmọ̀lò lórí ìlànà àti àwọn ìgbésẹ̀ mọfọ́lọ́jì yóò fún òǹkàwé ní ìmọ̀ titun lórí ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ ÀMÚYẸ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Ohùn tí ó jẹ́ àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí yìí ni pé ó jẹ́ kí á mọ ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹ̀ka èdè Yorùbá bákan náà ó tún jẹ́ kí á mọ àwọn ọ̀nà tí à ń gbà ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ ní ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà Síwájú sí i iṣẹ́ àkànṣe yìí tún jẹ́ kí a mọ iye ìró kọ́ńsónáǹtì àti ìró fáwẹ́lì tí a lè bá pàdé nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà Ó sí tún jẹ́ kí á mọ̀ pé kò sí ìró kọ́ńsónáǹtì ∫ nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà Bákan náà ó tún jẹ́ kí á mọ bí a ṣe ń pé àwọn ọ̀rọ̀ nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà Ní ìparí iṣẹ́ yìí jẹ́ kí á mọ̀ wí pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ nínú ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà tí a bá wò ó pẹ̀lú Yorùbá àjùmọ̀lò ÌMỌ̀RÀN FÚN ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Ibi tí a bá ìwádìí yìí dé ni ṣíṣe àlàyé lórí àwọn ìgbésẹ̀ tí à ń gbà ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀orúkọ ní ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà Ìwádìí ọjọ́ iwájú sì lè dá lé orí ìpele gírámà mìíràn bí i síntáàsì sìmáántììkì fonọ́lọ́jì ti ẹ̀kaèdè Ìgbómìnà tàbí ẹ̀ka èdè Yorùbá mìíràn Ìmọ̀ràn mi fún àwọn asèwádìí ọjọ́ iwájú ni pé ìmọ̀ kò pin sí ibì kan àti pé kò sí èdè tí kò ní ìpele gírámà tirẹ̀ kí wọ́n má ṣe kùnà láti wá ìmọ̀ kún ìmọ̀ ÌKÁDÌÍ Iṣẹ́ ìwádìí yìí fi hàn wá pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ nínú olórí ẹ̀ka èdè Yorùbá ìyẹn Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀ka èdè Ìgbómìnà nígbà tí a fi ojú mọfọ́lọ́jì wò ó tí a sì ṣe àlàyé lórí àwọn èdè méjèèjì pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ láti inú àwọn èdè yìí ÀKÓJỌ ORÚKỌ ÌWÉ Adéfilá Àfiwé Fonọ́lọ́jì Ẹ̀kaÈdè Ìgbómìnà àti Yorùbá Àjùmọ̀lò Iṣẹ́ Àṣegbágbá fún Gbígba Oyè Bíí Eè Ẹ̀kaẸ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Èdè Ilẹ̀ Nàìjíríà Ìlọrin Ìlọrin Adeyinka Jọ́nà Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àsà Yorùbá Nàìjíríà oi Àjàyì Ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá Ẹ̀dá Èdè Lítíréṣọ̀ àti Àṣà Ìjẹ̀búÒde Sebiotìmọ Awóbùlúyì Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ̀dá Ọ̀rọ̀ Yorùbá Awóbùlúyì Yorùbá Bamigbose A Fonọ́lọ́jì àti Gírámà Yorùbá Ìbàdàn Fajẹnyọ Jọ́nà Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àsà Yorùbá Nàìjíríà Olunlade T Èdè Yorùbá àti Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè Fọla ÌFOJÚ ÌMỌ̀ÌṢỌWỌ́LOÈDÈ ṢE ÌTÚPALẸ̀ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ ÒGÚNDÒKUN ADÉDOYIN O APÁ KAN IṢẸ́ ÀṢEKÁGBÁ FÚN Ẹ̀KỌ́ ÀKÀGBOYÈ NÍNÚ ÌMỌ̀ ÌPÌLẸ̀ Ẹ̀DÁ Bii Eè NÍNÚ ÈDÈ YORÙBÁ NÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ YUNIFÁSÍTÌ ÌLỌRIN ÌLỌRIN NÀÌJÍRÍÀ OṢÙ ÈBÌBÌ ỌDÚN ÌFỌWỌ́SÍ Iṣẹ́ àkànṣe yìí ni a ti kà tí a sì rí i pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè àti Èdè Nàìjíríà Yunifásítì Ìlọrin Ìlọrin ALÀGBÀ OT ÒKÉWÁNDÉ ỌJỌ́ ALÁBÒÓJÚTÓ OLÙYẸ̀WÒ ÌTA ỌJỌ́ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N ỌJỌ́ OLÓRÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁ ÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ÌFISỌRÍ Mo fi iṣẹ́ àṣekágbá yìí sọrí Ọlọ́run Olódùmarè àti àwọn òbí mi; Ẹnginíà Jimọh àti Aya rẹ̀ Hannah Ògúndòkun ÌDÚPẸ́ Yorùbá ló máa ń sọ pé oore yìí pọ ń ò mọ bí mo ṣe lè dúpẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àìmoore ni Èyí ló fà á tí mo fì fí ọpẹ́ àti ìyìn fún Olùwà Ọlọ́run mi ọba tó tóbi tó tún pọ̀ ni àánú Bí mo ni ẹgbẹ̀rún ahọ́n tí irun orí mi pọ̀ju yanrìn òkun lọ kò tó láti fi yín Olúwa Ọlọ́run mi fún àánú àti ooreọ̀fẹ́ rẹ̀ nínú ayé mi Mo dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Ọlọ́run Ọba Ìjìnlẹ̀ Ìfẹ́ atófaratì bí òkè Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé a kì í lé eku méjì kí a máa pàdánù ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wa nínú òwe wọn kan Ọlọ́run alààyè jẹ́ kí ó di mímọ́ fún mi pé pẹ̀lú ooreọ̀fẹ́ òun sí àwọn àyànfẹ́ ohun gbogbo ni ṣíṣe Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run aláàánú jùlọ tó ṣe ohun gbogbo fún mi lọ́nà ara ìyanu lẹ́nu ẹ̀kọ́ mi láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin Ó mú mi bẹ̀rẹ̀ layọ̀ ó sí tún mú mi parí layọ̀ àti àlàáfíà Bàbá mímọ́ ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ mímọ́ yín Ọpẹ́ mi pàtàkì tún lọ sí ọ̀dọ̀ olùkọ́ mi àtàtà olùkọ́ bí ẹ̀gbọ́n ẹní ọ̀gbẹ́ni Òkéwándé Olúwọlé Tẹ́wọ́gboyè ẹní tí ó jẹ́ olúdámọ́ràn àti alámòójútó mi fún àpilẹ̀kọ yìí Mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ yín fún ìlàkàkà yín ọgbọ́n àti oyè tí ẹ mú ro mi Ọlọ́run aláàánú jùlọ yóò jẹ́ kí ẹ máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo dáradára tí ẹ bá ń dáwọ́ lé o Àṣẹ Àánú Olùwà Ọlọ́run alààyè àti ooreọ̀fẹ́ rẹ̀ kò ni fi yín sílẹ̀ títí ọjọ́ ayé yín Àṣẹ Ẹ sé Olùwà a máa bu òróró ìyè sí orísun ọgbọ́n àti ìmọ̀ yín títí láì Bákan náà mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀gá mi ni ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀dá èdè àti èdè Nàìjíríà Mo dúpẹ́ fún akitiyan yín lọ́kọ́kanòjọ̀kan láti rí i pé mo di ohun tí mo dà lónìí yìí ìgbà olóore kì í fọ́ àwo olóore kì í fàya towó tọmọ ni kún ilé olóore ẹ ò ní ṣe àṣetì o Ọkọ ọba àdá ọba kò níí dáa yín lẹ̀sẹ̀ o Odò tó bá gbàgbé orísun rẹ̀ máa ń gbé ni ìdí nìyí tí ọpẹ́ mi pàtàkì ṣe tọ́ sí àwọn òbí mi Ẹnginia Jímọ̀ Ogundokun àti Aya rẹ̀ ogundokun Mo dúpẹ́ fún ìforítì àti àdúrà yín ẹ ṣeun ganan fún ìtìlẹhìn yín fún láti rí i pé mo ṣe àṣeyọrí lójú ẹ̀mí yín Ohun à ń láyọ̀lé kò ni bàjẹ́ iṣu ọmọ á jinná fún un yín jẹ o Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ kò ni jẹ́ kí oúnjẹ ọmọ jó yín lẹ́nu ò àlàáfíà àti Ayọ̀ lẹ ó fi jeun ọmọ o Àṣẹ Ọpẹ́ mi tún lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí mi nínú Olúwa àwọn bí i Ọmọ́wáre Ọladìpọ Ọládipo Bọlarinwa Àlàgbé Ronke Alonge àti àwọn tí ń kò ní le dárúkọ Ẹ ṣe púpọ̀ fún ẹ̀mí ìfẹ́ tí ẹ fi ń bá mi lò àti àdúrà yín lórí ayé mi ni ìgbà gbogbo àánú àti ooreọ̀fẹ́ Ọlọ́run alààyè kò ní fi gbogbo wa sílẹ̀ Àmín Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi tí a jọ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí ti Ọlọ́run tún ní ki á jọ parí layọ̀ àti àlàáfíà àwọn bí í Adebayọ Abiọla Ọsin ọpẹmipọ Akinwọlerẹ ọpẹ́yẹmi Awolola Damílọ́lá Ìfẹ́ Adeagbo Ọbatoye Julianah Olowolayemọ Adetutu àti àwọn yòókù tí ń kò lè dárúkọ tán Ẹ ṣeun Ọlọ́run á jẹ́ kí gbogbo wa ṣorííre láyé o Àmín Ní ìparí mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìyá mi Olùwàtobi Olùwàtosin àti Olùwàtìmílẹ́hìn fún ìfọwọ́ṣowọ́pọ̀ yín àdúrà mi ni e ikú kò ni pé wá fún àwọn òbí wa Ẹ ṣeun ÀṢAMỌ̀ Èròǹgbà iṣẹ́ àkànṣe yìí ni láti ṣe ìtúpalẹ̀ ewì Aṣọ Ìgbà pẹ̀lú tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè tí Dúró Adélékè kọ Ọ̀kan lára ewì àpilẹ̀kọ Yorùbá ni Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé onírúurú bí aṣọ alágẹmọ ni ewì àpilẹ̀kọ Yorùbá tó wà tí iṣẹ́ sì tí wà lórí wọn ṣùgbọ́n kò ti sí ẹní tí o lọ tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè rárá láti ṣe ìtúpalẹ̀ ewì yìí iṣẹ́ àkànṣe yìí jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ lórí ewì náà Èyí lọ fà á tí a fi yan iṣẹ́ àkànṣe yìí láàyò Ohun mìíràn tí ó tún fa ṣíṣe iṣẹ́ àkànṣe yìí ni láti wo bí Dúró Adélékè ṣe lo èdè nínú ewì Aṣọ Ìgbà Yàtọ̀ sí èyí ṣíṣe iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò fún òǹkọ̀wé ni ìwúrí láti lè gbé iṣẹ́ mìíràn tó tún dára ju èyí lọ jáde Àti wí pé èyí yóò sọ òǹkọ̀wé di ìlúmọ̀ká láwùjọ àwọn afèdèṣọnà Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ́ pé bí kò bá nídìí ẹ̀sẹ́ kan kì í ṣàdéédé ṣẹ́ lásán Òǹkọ̀wé tàbí oníṣẹ́ ọ̀nà lítíréṣọ̀ kì í sà dédé gbé iṣẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ láì ni Èròǹgbà kan tí ó fẹ́ kí àwọn òǹkọ̀wé tàbí àwùjọ rí nínú iṣẹ́ rẹ̀ Ọ̀kẹ́ àìmọye ni kókó tí ó ṣúyọ nínú ewì Aṣọ Ìgbà tí Dúró kọ Bákan náà ìgbékalẹ̀ Dúró Adélékè nínú ewì rẹ̀ wà ní ṣíṣẹ̀ntẹ̀lé tí àwọn kókó tí ó fẹ́ là hàn àwùjọ kò fi dàrú Ní àfikún ojúlówó èdè Yorùbá ni òǹkọ̀wé lò bí i; àfiwé àwítúnwí àti ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Yorùbá Tíọ́rì tí a ṣàmúlò fún ìkẹsẹ̀jarí iṣẹ́ àkànṣe yìí ni tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè Òdiwọ̀n tí a sì ṣàmúlò fún ìtúpalẹ̀ rẹ̀ ni ìtayọ ìṣewẹ́kú àti ìfúnnítumọ̀ A sí rí i pé tíọ́rì yìí ni yóò wúlò púpọ̀ fún iṣẹ́ yìí nítorí pé ohun tí ó jọ ohun la fi ń wéra èpo ẹ̀pà ló jọ pósí ẹ̀lírí Ìṣọwọ́loèdè ni ó bá iṣẹ́ yìí mú láti lè jẹ àfikún ìmọ̀ wa lórí ìṣọwọ́loèdè Bẹ́ẹ̀ ni àbájáde ìwádìí yìí yóò jẹ́ kí a lè mọ àwọn ibi tí irú iṣẹ́ ìwádìí báyìí tún ti le wáyé fún ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá ÀTẸ ÀKÓÓNÚ Àkọlé Ìfọwọ́sí Ìfisọrí Ìdúpẹ́ Àṣamọ̀ Àtẹ Àkóónú ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Ìfáàrà Èrèdí Iṣẹ́ Ìwádìí Ibi tí Ìwádìí Gbòòrò Dé Ọgbọ́n Ìwádìí Àǹfààní Iṣẹ́ Ìwádìí yìí Ètò Ìwádìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN Ìfáàrà Èdè Èdè àti Ìṣọwọ́ Lítíréṣọ̀ Ewì Tíọ́rì Ìṣàmúlò Tíọ́rì Ìṣọwọ́loèdè ORÍ KẸ́TA ÌTAYỌ ÈRÒJÀ INÚ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ Ìfáàrà Ìtayọ Kókó Inú Aṣọ Ìgbà Ìtayọ Ìṣẹ̀lẹ̀ Inú Aṣọ Ìgbà Ìtayọ Akópa Inú Aṣọ Ìgbà Ìtayọ Wúnrẹ̀nèdè Ìfáàrà Ìtayọ Wúnrẹ̀nèdè Inú Aṣọ Ìgbà ORÍ KẸ́RIN ÌṢEWẸ́KÚ ÈRÒJÀ EWÌ INÚ AṢỌ ÌGBÀ Ìfáàrà Ìṣewẹ́kú ajẹmọ́ Kókó Ìṣewẹ́kú Ajẹmọ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Ìṣewẹ́kú Ajẹmọ́ Akópa Ìṣewẹ́kú Ajẹmọ́ Wúnrẹ̀nèdè ORÍ KARÙNÚN ÌFÚNNÍTUMỌ́ INÚ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ Ìfáàrà Ìlànà fún Fifún Iṣẹ́ Ọ̀nà ní Ìtumọ̀ Ìtumọ̀ Tààrà Ewì Aṣọ Ìgbà Ìtumọ̀ Àkànlò Ewì Aṣọ Ìgbà Ìṣàfọ̀ di tẹni Ewì Aṣọ Ìgbà ORÍ KẸFÀ ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ Ìfáàrà Ìsọníṣókí Àbọ̀ Ìwádìí Àmúyẹ àti Àléébù Iṣẹ́ Ìwádìí yìí Ìmọ̀ràn fún Ìwádìí Ọjọ́ Iwájú Ìkádìí Àkójọ Orúkọ Ìwé ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌFÁÀRÀ Kí àgbàdo tó dáyé ki ní kan sáà ni adìẹ ń jẹ́ èrò àwọn Òyìnbó aláwọ̀ funfun pé Yorùbá kò ní lítíréṣọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá Àwọn Yorùbá ní lítíréṣọ̀ ti wọn tí ewì sì jẹ́ ọ̀kan lára rẹ̀ Ṣùgbọ́n kò sí ní àkọsílẹ̀ Ewì àkọ́kọ́ Dúró Adélékè ni Aṣọ Ìgbà èyí sì ni iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò ṣàmúlò láti ṣe ìtúpalẹ̀ tó jinlẹ̀ lé lórí pẹ̀lú tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè Fífi ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè ṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ jẹ́ tíọ́rì kan pàtàkì nínú àwọn onírúurú tíọ́rì tí ó wà fún ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ lítíréṣọ̀ lọ́kànòjọ̀kan Àkààmọye àwọn onímọ̀ lo ti ṣàmúlò tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè ní èdè Gẹ̀ẹ́sì lára wọn ni Ní èdè Yorùbá ọ̀pọ̀ ni àwọn lámèyítọ́ iṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ tó ti ṣe àmúlò tíọ́rì yìí láti ṣe ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ lítíréṣọ̀ kan tàbí òmíràn Ẹni àkọ́kọ́ ni Babalọlá Láṣebìkan Bámisilẹ̀ Awóyalé Ọlábọ̀dé Adégbìtẹ́ Àjàyí Y Bámisilẹ̀ R àti Ọdẹ́bùnmi W lo ìwé Láti fi ṣe àtẹ̀gùn iṣẹ́ rẹ̀ Níbẹ̀ ló ti fi àwọn èròjà ìṣọwọ́loèdè ewì Yorùbá hàn Ní pàtàkì ìfidọ́gba Ó ṣe àfiwé àbùdá yìí pẹ̀lú èròjà ewì ilẹ̀ Hébérù Babalọlá ṣíṣe lórí ìjálá pẹ̀lú wíwo àbùdá ààtò ti ìjálá Yorùbá máa ń ni Láṣebìkan wo pàtàkì ohùn nínú ewì Yorùbá Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí àwọn iṣẹ́ yìí bí èyí to fi tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè ṣe àtẹ̀gùn síbẹ̀ a ní láti sọ pé wọn kò gùnlé ọgbọ́n kan pàtó Nítorí ìdí èyí ní a ṣe làkàkà láti ṣe àmúlò àwọn ohun èlò ìṣọwọ́loèdè Gẹ́gẹ́ bí èyí ti wọ́n tí ń lò tẹ̀lé Ṣùgbọ́n ìtayọ ìṣewẹ́kú àti ìfúnnítumọ̀ ní a ó ṣàmúlò nínú iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bí kò bá nídìí obìnrin kì í jẹ́ Kúmólú Ó ni ìdí pàtàkì tí a fi yan tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè láàyò fún iṣẹ́ lámèyítọ́ lórí ewì àpilẹ̀kọ Aṣọ Ìgbà tí Dúró Adélékè kọ Ohun àkọ́kọ́ tó kókó gún mi ni kẹ́ṣẹ́ inú ni pé mo wòye pé gẹ́gẹ́ bí ewì àpilẹ̀kọ tó jẹ́ ti ìgbàlódé tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè lọ lè ṣe ọ̀fintótó àlàyé ti yóò tú iṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò gbogbo èròjà tí òǹkọ̀wé fi èdè ṣọjọ̀ sínú ìwé rẹ̀ Kì í ṣe pé mo sọ pé kò sí àwọn tíọ́rì mìíràn tó tún wúlò fún ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé kì í ṣe kókó inú ewì yìí nìkan tàbí ọnàèdè nìkan ni a fẹ́ yẹ̀wò Bákan náà a dáwọ́lé iṣẹ́ àkànṣe yìí láti fa ọgbọ́n kan tàbí òmíràn yọ àti láti tọ́ka sí àléébù tàbí àmúyẹ tí ó wà nínú ewì Aṣọ ìgbà Èyí nìkan kọ́ lílo tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè yóò fún wa ni àǹfààní láti fi kún ìdàgbàsókè ìmọ̀ wa nípa èdè tí òǹkọ̀wé fi gbé ewì rẹ̀ kalẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni a jẹ́ kí a mọ̀ bí a ṣe ń lọ èdè nínú onírúurú ọ̀nà àti láti tún mọ àwọn ohun tí a lè fi èdè ṣe Ní àkóótán irú iṣẹ́ yìí yóò fún ni ni ìmọ̀ kíkún nípa ìjẹyọ àwọn àbùdá ìṣọwọ́loèdè ti iṣẹ́ yìí fi ṣàtẹ̀gùn IBI TÍ ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ Níwọ̀n ìgbà ti a kò ti lè rí kọjá ohun tí òǹkọ̀wé gbé lé wa lọ́wọ́ nípaṣẹ̀ èdè nínú iṣẹ́ rẹ̀ ewì Aṣọ Ìgbà wo ibi ti ọwọ́jà iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò de Èyí ni yóò fún wa láàyè láti lè sọ ìṣọwọ́ òǹkọ̀wé nínú iṣẹ́ yìí ohun tí ó jẹ́ wa lógún nínú iṣẹ́ yìí ni láti ṣàyẹ̀wò fínnífínní nípa ìṣọwọ́loèdè òǹkọ̀wé ewì Aṣọ Ìgbà látàrí àti fi àbùdá tí a yàn láàyò wo èdè òǹkọ̀wé Lọ́nà mìíràn iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò ṣe àgbéyẹ̀wò èròjà díẹ̀ nínú òdiwọ̀n ìṣọwọ́loèdè pàápàá ìtayọ Ìṣewẹ́kú àti ìfúnítúmọ̀ Nítorí àkókò àti ààyè tí a ní fún iṣẹ́ yìí a ó ni lè ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn èròjà yòókù tí ń bẹ nínú ìṣọwọ́loèdè ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ Onírúurú bí i aṣọ alágẹmọ ni ọgbọ́n ìwádìí jẹ́ onírúurú ọgbọ́n ìwádìí yìí sì ni ènìyàn lè lò láti fi ṣe iṣẹ́ àkànṣe Ọ̀kan pàtàkì lára ọgbọ́n ìwádìí tí a kò le fojú rénà ni lílọ sí yara ìkàwé Kí iṣẹ́ ìwádìí yìí lé ìpìlẹ̀ tó lọ́ọ̀rìn Bákan náà a ó ṣàmúlò èròjà bí i pépà àpilẹ̀kọ wíwo jọ́nà kíka àwọn ìwé ìléwọ́ lóríṣìíríṣìí àti àwọn ìwé àtìgbàdégbà gbogbo Yàtọ̀ sí èyí a ó ṣàmúlò tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè pẹ̀lú Púpọ̀ àwọn àwòmọ́ àbùdá tí a ṣàyàn bí ìtayọ ìṣewẹ́kú àti ìfúnítumọ̀ ni a ó wò fínífíní pẹ̀lú ipa ìjẹyọ irú àwọn èròjà wọ̀nyí fún ìkẹ́sẹjárí iṣẹ́ yìí ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Ọ̀kanòjọ̀kan ni àǹfààní tí iṣẹ́ àkànṣe yìí lè mú bá ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá àti fún àwọn òǹkọ̀wé alátinúdá oníṣẹ́ lítíréṣọ̀ pàápàá ewì Lára àwọn àǹfààní tí ó lé mú wá ni pé yóò sí ojú àwọn òǹkọ̀wé tàbí akẹ́kọ̀ọ́ sí ìmọ̀ ní pa bí èdè ṣe ń ṣíṣe ní gbogbo ọ̀nà ìlò rẹ̀ Bákan náà iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò jẹ́ àfikún ìmọ̀ wa lórí ìṣọwọ́loèdè pàápàá jùlọ bó ṣe kan ewì àpilẹ̀kọ tíṣẹ́ yìí fi ṣàtẹ̀gùn ìwádìí Síwájú sí i iṣẹ́ àkànṣe yìí tún lè sọ òǹkọ̀wé di ìlúmọ̀kà láwùjọ àwọn akewì Nítorí pé ṣíṣe iṣẹ́ bí irú èyí yóò jẹ́ kí a tún ní ìmọ̀ kíkún nípa akewì tàbí òǹkọ̀wé bẹ́ẹ̀ Lọ́nà mìíràn àbájáde ìwádìí yìí yóò jẹ́ kí a lè mọ àwọn ibi ti irú iṣẹ́ ìwádìí báyìí tún ti lè wáyé fún ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá ÈTÒ ÌWÁDÌÍ Orí mẹ́fà ni iṣẹ́ àkànṣe yìí pín sí Orí kìíní yo ṣàgbéyẹ̀wò èrèdí iṣẹ́ ìwádìí ibi tí ìwádìí gbòòrò dé àǹfààní ìwádìí lẹ́yìn rẹ̀ wa ní ètò ìwádìí tó jẹ́ ìkádìí fún orí yìí Ní orí kejì ni a o ti wo Aáyan ọ̀mọ̀ràn lórí ohun tí ọ̀kanòjọ̀kan onímọ̀ tí sọ lórí èdè ìsọ̀wọ́ àti lítíréṣọ̀ pẹ̀lú ewì tí a ó sì fi tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè kásẹ̀ orí yìí Síwájú sí i àtúpalẹ̀ ewì Aṣọ Ìgbà ni orí kẹ́ta ní bẹ̀ ni a ó ti wo ọ̀kan lára òdiwọ̀n ìṣọwọ́loèdè Ìtayọ nínú kókó ìṣẹ̀lẹ̀ akópa àti wúnrẹ̀n èdè Bákan náà òrí kẹ́rin àti karùnún jẹ́ ìtẹ̀síwájú àtúpalẹ̀ ewì Aṣọ Ìgbà Ní orí yìí ni a ó ti wo ìṣewẹ́kú àti ìfúnítumọ̀ lára òdiwọ̀n ìsọ̀wọ́lọèdè A ó wo kókó wúnrẹ̀nèdè akópa àti ìṣẹ̀lẹ̀ ewì náà bó ṣe ṣe wẹ́kú sí pẹ̀lú wíwo oríṣìí ọ̀nà tí ìjẹyọ ìfúnítumọ̀ lè gbà wáyé fún ìkẹ́sẹjárí afọ̀ Bí a ṣe mọ̀ pé kò sí ohun tí ó ni ìbéèrè tí kì í ni òpin Bẹ́ẹ̀ náà ni orí kẹfà ni yóò parí iṣẹ́ àkànṣe yìí Ibẹ̀ ní a ó ti jábọ̀ ìwádìí ni ṣókí A ó sì tọ́ka sí àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ àkànṣe yìí pẹ̀lú ìmọ̀ràn tí yóò wúlò fún ìwádìí ọjọ́ iwájú Nígbà tí ìkádìí àti àkójọ ìwé kásẹ̀ ohun gbogbo nílẹ̀ lórí iṣẹ́ àkànṣe yìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN ÌFÁÀRÀ Orí yìí dálé oríṣìíríṣìí ohun tí àwọn onímọ̀ ti sọ Bí ó tí jẹ́ pé kì í jẹ́ ti bàbá tí ọmọ kó má láàlà Ìṣọwọ́loèdè ni abala yìí yóò fi ṣe òdiwọ̀n àwọn iṣẹ́ tó le ṣe ìrànwọ́ láti mọ ohun kan tàbí òmíràn lórí èdè àti ìṣọwọ́ ewì pẹ̀lú lítíréṣọ̀ niṣẹ́ yìí yóò gbéyẹ̀wò pẹ̀lú àlàyé lórí ìhà tí a kọ sínú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ ÈDÈ Pàtàkì ní èdè jẹ́ láwùjọ ènìyàn kò sí ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn Yorùbá jẹ́ ìran tó mọ ẹ̀wọ̀n èdè wọ́n mọ òté èdè pẹ̀lú Wọ́n kì í déédé sọ̀rọ̀ ṣákálá bí ọbẹ̀ àtẹ́ pẹ̀lú ọgbọ́n inú àti iyè ikùn niwọ́n fi máa ń lo èdè Wọ́n ni ìpèdè ló bá àsìkò àti ìṣẹ̀ṣe kọ̀ọ̀kan mú Èdè awo yàtọ̀ sí ti ọ̀gbẹ̀rì Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Yorùbá bá ń pèdè wọ́n máa ń fi àwọn èròjà èdè tó wọ ni lára gbé e kalẹ̀ Abọ́dúndé nínú Ajelétí rí èdè bí ohun tí ó ń tí ẹnu ènìyàn jáde kí a tó le sọ pé irú ẹní bẹ́ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ Èyí ni pé ẹnu èèyàn ni èdè ti máa ń jáde Bákan náà Adeboyejẹ rí èdè bí ọ̀nà tàbí ìlànà kan tí àwọn ènìyàn gbà láti máa tẹ̀lé fi ronú kẹ́dún yọ̀ tàbí ṣe àwọn nǹkan mìíràn yálà nípa sísọ tàbí ìwé kíkà lọ́nà tí ó fi lè yé ẹní tí kò bá mọ ìlànà rẹ̀ Èrò yìí náà ni Adéníyì àti Ọnàdipẹ̀ wí lórí èdè wọn ni ohun èlò ti àwùjọ kọ̀ọ̀kan fi ń ni ìbáṣepọ̀ tó gúnmọ́ pẹ̀lú ara wọn Ohun tí a sọ jáde lẹ́nu tí a lè fi etí gbọ́ tí a sí ṣe àmúlò ẹ̀yà ara wa kan ni ìbámu pẹ̀lú ìró kọ́ńsónáǹtì àti fáwẹ́lì irú èdè bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú mọ òfin àti àdéhùn àwọn elédè Ohun tí wọ́n gbìyànjú láti sọ ni pé ẹ̀bùn pàtàkì ni èdè jẹ́ fún ènìyàn láti máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ látàrí àdéhùn ti ẹnu kò lé lórí Ọ̀gbẹ́ni Ajéléfí ṣe àkíyèsí pé Èdè dàbí ẹ̀mí fún ọmọ ènìyàn àti pé odi tàbí aditi tì ki`o le sọ tàbí gbọ́ èdè àwùjọ rẹ̀ pàdánù àǹfààní àsọyé pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ Nítorí ìdí èyí èdè ṣe pàtàkì fún ìwà láàyè àti ìdàgbàsókè ẹ̀dá Láìṣe àníàní a ó rí i pé èdè ṣe pàtàkì nínú ayé ẹ̀dá ènìyàn láwùjọ Bí kò bá sí èdè láyé òtúbántẹ́ nílẹ̀ ayé ì bá jásí Bí a bá sí wò ó jinlẹ̀ a ó gbà wí pé òpómúléró kan pàtàkì ni èdè jẹ́ ni gbogbo ohun ti a bá ń ṣe láyé Àwọn onímọ̀ bí rí èdè gẹ́gẹ́ bí ohun èlò Ìṣàlàyé láàrín àwùjọ nípasẹ̀ ìró tí ó jáde nínú ẹ̀dọ̀fóró wọ́n ní Èrò àwọn onímọ̀ wọ́n yìí jọra pẹ̀lú èrò Ajélétí Nítorí wọ́n rí èdè bí ohun èlò fún igbejade èrò tó dá lórí ohun mẹ́ta gbòógí ènìyàn èrò ọ̀kan àti ìbáraẹnísọ̀rọ̀ Èyí ni wipe tí ohun mẹ́ta wọ̀nyìí kò bá ṣẹlẹ̀ a kò lè pè é ní èdè kí èdè báyìí Èyí ní wí pé èdè kì í ṣọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ nìkan ohun àmúṣòggo gidi ni ibi ìṣemọlọ́jọ̀ sí Gbùngbùn ọgbọ́n ọ̀nà àbáyọ fún òtítọ́ àti atọ́nà fún àṣà ni A ó rí i pé Yorùbá kì í dédé sọ̀rọ̀ lásán láì yiri rẹ̀ wò bóyá ó wà ní ìbámu pẹ̀lú otun tí wọ́n ń lò ó fún Èdè tí a ń lò fún ọba yàtọ̀ sí ti ìjòyèn èdè ìjòyè yàtọ̀ sí ti ènìyàn lásán Àṣàyàn èdè tí a ń lò fún àgbà yàtọ̀ sí ti ọmọdé Gbogbo èyí ló sodo sínú àṣà Bí wọ́n bà sí fẹ́ pa àwọn ènìyàn kan run Kí wọ́n gba èdè wọ́n lọ́wọ́ wọ́n ní kíákíá ni èyí yóò ṣe é ṣe Bákan náà Oyeyemi sọ pé Ó túmọ̀ sí pé èdè ni ohun tí à ń lò láti gbé ìfẹ́ inú wa jáde a fí ń pa àṣẹ sọ òtítọ́ parọ́ èyí tí ó ń nípa lórí olúgbọ́ wa àti pèṣè fún ìmọ̀lára èyí tí a kò ní ní bí kóbá sí èdè Ní ìtẹ̀síwájú pearson àti àwọn tókù rí èdè gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ àmìn àpapọ̀ ìró tàbí ọ̀rọ̀ tí ó ní ìtumọ̀ gbòógì tí ó sí ni ìlànà kan tí ó ń tẹ̀lé fún ìbánisọ̀rọ̀ Gbogbo atótónu àwọn onímọ̀ lórí èdè ni wí pé èdè dúró bí ọ̀nà tí ẹ̀dá ènìyàn ń gbà ṣàlàyé ara rẹ̀ fún ìtàkurọ̀ṣọ àti àṣepọ̀ tó dán mọ́rán láàrín ènìyàn Èdè tí à ń wí yìí ni ó ya ènìyàn sọ̀rọ̀ sí ẹranko nítorí pé a ni èdè a mú wọn sìn Ẹlẹ́dàá sí fi wá jọba lórí wọn Yorùbá ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà mìíràn tí wọ́n gbà bá ara wọn sọ̀rọ̀ lára rẹ̀ ni ìfé ṣíṣú àlè pípa ìlù lílù imú yíyín àti ẹ̀gẹ̀ yíyẹ̀ Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyìí yàtọ̀ sí èdè nítorí pé èdè ni àsopọ̀ gbólóhùn Ṣùgbọ́n àwọn àmì tí a tọ́kasí wọ̀nyìí kì í ṣe ohun tí a mọ̀ kárí ayé ó ye rẹ̀ sí le sọ̀rọ̀ tí a kó bá rí èdè láti fi ṣàlàyé rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ohun tí àwọn onímọ̀ ń sọ pé yóò sọ̀rọ̀ láti túmọ̀ bí a kòbá lọ èdè Èdè tí à ń wí yìí náà ní àwọn kan pè ni afọ̀ Ohun náà sì ni Awóyalé ṣàlàyé gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí a sọ jáde tàbí tí a kọ sílẹ̀ tóju ẹyọ gbólóhùn lọ tó sì ni ìdí pàtàkì tí a fi gbé jáde ní à ń pè ni afọ̀ Afọ̀ àwòrán tó gbé kalẹ̀ ni yìí ÈRÒJÀ INÚ AFỌ̀ KÍKÚN ÈDÈ ÀTI ÌṢỌWỌ́ Èdè ni irinṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ fún oníṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ Nínú rẹ̀ a kòlè kóyán èdè àti ìṣọwọ́ kéré Nítorí ohun ni òǹkọ̀wé yóò fi ṣe àgbékalẹ̀ èrò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn kókó tí ó ṣodo sínú ìwé rẹ̀ Nítorí náà ó yẹ́ kí a wo ohun tí àwọn onímọ̀ pé ní ìṣọwọ́ Ọ̀kanòjọ̀kan àwọn onímọ̀ ló ti sọ ohun kan tàbí òmíràn lórí ohun tí ìṣọwọ́ jẹ́ Nǹkan tí àti ń sọ ní pé ìṣọwọ́ ní ọ̀nà ìgbéjáde èrò tó tọ́ tí ó sí ṣe é ṣe ní pa sísọ ohun tí ó tọ́ ní ọ̀nà tí ó tọ́ jùlọ Èyí ni pé yíyàn ni èdè oníṣe ọ̀nà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ Yálà ewì eré onítàn àti eré oníṣe Ìpeleǹpele sì ni a lè gbà wo yíyàn ìṣọwọ́ yìí pẹ̀lú Bákan náà túmọ̀ ìṣọwọ́ báyìí Tí ó túmọ̀ sí pé ìṣọwọ́ ni lílo èdè lọ́nà tòótọ́ pàápàá jùlọ nínú ọ̀rọ̀ geere yálà láti ṣẹ̀dá gbólóhùn tàbí ru u ìmọ̀lára sókè Èyí tó ni ṣe pẹ̀lú lílo agbára láti ni èrí tó rinlẹ̀ lọ́nà tí yóò gbà yé ènìyàn Ohun kan pàtàkì tí mo ṣe àkíyèsí ní wí pé bí òǹkọ̀wé òṣèré tàbí akéwì kan bá ní iṣẹ́ kan tí ó bá fẹ́ rán sí àwùjọ Ohun èlò pàtàkì tí wọ́n má a ń ṣe àmúlò ní èdè àti ìṣọwọ́ Yálà wọ́n kò ọ́ sílẹ̀ ní o tàbí pé wọ́n gún orí ìtàgé láti ṣeré Wọ́n gbọdọ̀ ṣe àmúlò èdè àti ìṣọwọ́ Nínú àríwòye Ayọ̀ Ọpẹ́fẹ́yíntìmí ó ni ìṣọwọ́ ni ìyàtọ̀ láàárín ogúnlọ́gọ̀ àwọn nǹkan tó jọra wọn bí ìmumu Nǹkan tí Ọpẹ́fẹ̀yìntìmí ń sọ ní pé kò sí ohun tí kò ní ìsọ̀wọ́ a lè sọ̀rọ̀ nípa ìsọ̀wọ́ ìwà wíwú èyí ni ìwà ti a ti mọ̀ ọ̀n mọ ẹnìkan tó ti jẹ́ bárakú tí ó sí máa ń wù ni gbogbo ìgbà bẹ́ẹ̀ náà ní ìsọ̀wọ́ òǹkọ̀wé pàápàá wà Èyí ni ṣe pẹ̀lú ẹwà tàbí ète iṣẹ́ ọ̀nà aláwòmọ́lítíréṣọ̀ O Toole ṣàlàyé ìsọ̀wọ́ báyìí ni tirẹ̀ Nǹkan tó ń ṣàlàyé ni pé àgbéyẹ̀wò ìsọ̀wọ́ kò le tẹ̀síwàjú láìṣe àgbéyẹ̀wò èdè nítorí àsomọ̀ tó ni pọn tó wà láàárín wọn nínú ìwé túmọ̀ ìṣọwọ́ báyìí Nǹkan tí ń sọ ni pé ìṣọwọ́ jẹ́ ọ̀nà tí à ń gbà ṣe àfihàn èrò ọ̀kan nínú ohun tí a kọ sílẹ̀ tàbí èyí tí a sọ lẹ́nu Nínú ìwé yaágbó túmọ̀ ìṣọwọ́ báyìí ó jẹ́ ọ̀nà tí òǹkọ̀wé ń gbà lọ ọ̀rọ̀ láti ṣẹ̀dá iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ọ̀rọ̀ kan máa tẹ̀lé òmíràn ìpín afọ̀ kan yóò sì já sí òmíràn Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ní ìṣọwọ́ rìn ẹnìkan aṣọ wíwọ̀ irun gígé tàbí dídì Tí à ń gba oríṣìíríṣìí ọ̀nà ṣe iṣẹ́ ìṣẹ̀ṣe bí gbẹ́nàgbẹ́nà mọlémọlé afíngbá ìlù lílù ẹní híhun tí gbogbo wọn sí ní ìṣọwọ́ tí a ń gbé wọn jáde bẹ́ẹ̀ náà ni òǹkọ̀wé tàbí akewì kan ní ọ̀nà ìṣọwọ́ tí a fi lè da a mọ̀lọ́tọ̀ Ìsọ̀wọ́ gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ àti ìṣọwọ́ fèsì kàn ló yàtọ̀ sí èkejì Ohun ni jẹ́ kó yé wa pé ayẹyẹ kọ̀ọ̀kan ló máa ń darí èdè àmúlò Èyí ní ó jẹ́ kí ó gba gbogbo aṣafọ̀ tàbí òǹkọ̀wé ní ó jẹ́ elédè púpọ̀ tàbí oníṣọwọ́ púpọ̀ Nítorí ibi ayẹyẹ tí wọ́n bá bára wọn ni yóò sọ àṣàyàn èdè tí wọn yóò ṣàmúlò Èyí ni yóò mú kí òǹkọ̀wé ṣàkíyèsí àwọn tó ń ránṣẹ́ èdè sí àti èròǹgbà iṣẹ́ tí ó ń rán Nígbà tí ó ní Fún ìdí pàtàkì yìí bí ìgbà tí a kí Ìgè ní àdùbí ti a sí kí ojó ni akítíkorí ọ̀nà ọ̀fun ó gboogun ẹja ní ìṣọwọ́ àti èdè jẹ́ fún òǹkọ̀wé tàbí akéwì máa ń ṣàmúlò láti dá àrà sára iṣẹ́ ọ̀nà wọn Èyí ló sí mú ìyapa wà láàrín èdè ojoojúmọ́ àti èdè lítíréṣọ̀ LÍTÍRÉṢỌ̀ Ọkẹ́ àìmọye àwọn lámèyítọ́ ni wọ́n tí ṣe iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ ni èdè Yorùbá Tí wọ́n sí fún ní oríkì báyìí Agbònà F sọ pé Àrògún àti àròjinlẹ̀ àwọn ènìyàn ni pa ilé ayé ni Àfọkànrò àti onírúurú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ìgbé ayé ọmọ ẹ̀dá àṣetì àti àṣeyọrí wọn èrò ènìyàn ní pa ayọ̀ àti ìbànújẹ́ ilé ayé àjálù tí ó ń dé bá ọmọ ènìyàn ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà àti ọ̀nà àbáyọ ni ohun tí lítíréṣọ̀ ń kò lórin Èyí ní pé nínú gbogbo ìgbésíayé èdè láyé ni lítíréṣọ̀ ti ń jẹyọ Àwọn mìíràn sọ pé lítíréṣọ̀ ni àkójọpọ̀ èrò ìmọ̀ ọgbọ́n àṣà ẹ̀sìn ìbágbépọ̀ láwùjọ àti ohun yòówù tí a bá mọ̀ ni pa ẹ̀yà kan tàbí àwùjọ kan ohun yòówù tí ó bá ń ṣe àkíyèsí àwùjọ àti ìbágbépọ̀ ẹ̀dá láwùjọ ni lítíréṣọ̀ òun ní ìrànlọ́wọ́ fún àtúnṣe ayé Èyí ni èrò Akínjogbìn pé; Lítíréṣọ̀ jẹ́ àkójọpọ̀ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ni èdè kan tàbí òmíràn ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó já sí ewì ìtàn àlọ́ ìyànjú ìròyìn tàbí eré onítàn eré akọ́nilọ́gbọ́n lórí ìtàgé lítíréṣọ̀ le wà nínú ọpọlọ àwọn ọ̀mọ̀ràn Ó jẹ́ pé lítíréṣọ̀ ni ọ̀rọ̀ tàbí èdè ọgbọ́n tí a fi ohun gbé jáde ni àwùjọ sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀ kí ó tó di kíkọ́ sílẹ̀ nípa ìlànà mọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà ní àwùjọ alákọ̀wé Èrò yìí tẹ̀síwàjú nígbà tí Babalọlá sọ pé lítíréṣọ̀ ni ìlànà tí à ń gbà sọ fún ayé gbọ́ ohun tí ó jẹ ni lọ́kàn nípa àyíká Èyí tí a gbé kalẹ̀ lọ́nà tààrà tàbí lọ́nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí lọ́pọ̀ ìgbà láì dárúkọ pàtó àwọn ẹní ti ọ̀rọ̀ kàn ganan Ṣùgbọ́n tí àṣàyàn ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ pẹ̀lú ohun tó fẹ́wa fún ohun tí à ń sọ náà ń ṣáábà jẹ ẹní tí ń ṣe àgbékalẹ̀ lógún Bákan náà nínú ìwé rẹ̀ tó pé ní sọ báyìí ní pa lítíréṣọ̀ Ohun ti jẹ́ kí ó di mímọ́ fún wa ni pé lítíréṣọ̀ kì í ṣe nǹkankan ṣákálá tó sọ mọ́ ayé ọ̀rọ̀ ní pa ayé ẹnìkan pàtó ni Èyí ní pé jígí àwùjọ ni lítíréṣọ̀ jẹ́ tí ó ṣe ìgbé jáde ìhùwàsí ìṣeṣí àti gbogbo ohun àtubọ̀tán tí à ń ba pàdé nínú Ìrìnkèrindò ọmọ ẹ̀dá ènìyàn ni iléayé Ohun ló sí ṣe àfihàn gbogbo ohun tó ń lọ nínú ayé nípasẹ̀ ìgbésí ayé àwa ènìyàn Tí a bá wo èrò Ògúnṣínà ó fẹ́rẹ̀ kín ohun tí sọ lẹ́yìn nígbà tí ó ní Nǹkan tí èyí túmọ̀ sí ni pé Lítíréṣọ̀ níí ṣe palu ènìyàn àti àwùjọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí okùn agbára èrò ènìyàn bí ìṣesí rẹ̀ tirí ní àwùjọ ìmọ̀ òun alara àti àwùjọ tó ti bá ara rẹ̀ Èyí túmọ̀ sí pé láì sí ènìyàn àkọlé ní àwùjọ bẹ́ẹ̀ náà ni a kò lè ní lítíréṣọ̀ tí a o fi yangàn èyí ni pé bí eégún ṣe wọnú ẹran tí ẹran wọnú eégún náà ni lítíréṣọ̀ àti àwùjọ wọnú ara wọn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ó sì ṣe é yà sọ́tọ̀ Nínú ìwé kí lítíréṣọ̀ báyìí Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé lítíréṣọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èrò àti ìlànà tí à ń gbà fi ìmọ̀lára iṣẹ́ àti ọgbọ́n hàn sí aráyé yálà nípa orin kíkọ́ iṣẹ́ ọnà ìtàn ààlọ́ ewì ọ̀rọ̀ geere àti ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Ní àfikún a rí i pé gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ yìí ṣe sọ a rí pé gbogbo èyí ní o jẹyọ nínú ìgbésíayé àwọn babańlá wa bí àgbẹ̀ tí ń bẹ lóko yóò máa sún ìjálá gẹ́gẹ́ bí orin amúṣẹ́yá bẹ́ẹ̀ náà ni ìyá àbúrò tí ń kọrin gẹ́gẹ́ bí orin ìrẹmọ Èyí ní pé bí àwọn Yorùbá ṣe ń dàgba náà ni lítíréṣọ̀ ti ba wọn dàgba tí wọn sí hun ṣe àmúlò rẹ̀ lẹ́yìn iṣẹ́ ọjọ́ọ́ wọn Ohun ni òǹkọ̀wé sàjọ gẹ́gẹ́ bí èròjà láti gbé iṣẹ́ ọ̀nà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ kalẹ̀ Èyí ni ọ̀pọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ sì ti gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ káàkiri àgbáyé EWÌ Àyẹ̀wò lítíréṣọ̀ Yorùbá fihàn pé ewì kì í ṣe nǹkan kékeré nínú àṣà ilẹ̀ ká àárọ̀ẹjíire Nínú rẹ̀ ni a tí lè rí àwọn ohun àmúṣagbára ilẹ̀ Yorùbá Irú agbára tí à ń wí ni ọgbọ́n ayé jọ́un àti ti òde òní ti Yorùbá ń lò fún ètò òṣèlú ìṣe iṣẹ́ oògùn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ òye àti gbogbo ọgbọ́n amúlùútòro tó jẹ wọ́n lógún nínú gbogbo ìgbésíayé wọn Ewì ọ̀hun sí wá pín sí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Èyí àkọ́kọ́ ni ti lítíréṣọ̀ alohùn gẹ́gẹ́ bí Ìyẹ̀rẹ́ifá Ìjálá Ẹ̀ṣà Eégún Ègè Ṣàngópípè àti ọ̀pọ̀ ewì alohùn mìíràn tó wà fún lílò níbi ayẹyẹ ètò ìbílẹ̀ Àtẹnudẹ́nu ni àwọn ewì wọ̀nyí Èyí èkejì ni ewì àpilẹ̀kọ ewì àpilẹ̀kọ wà fún àkàgbádùn àwọn tó ní ìfẹ́ sí èdè Yorùbá nínú ìwé Ohun kan tó ṣe pàtàkì ni pé ewì ti di omi ara àti ẹ̀jẹ̀ ara àwọn Yorùbá Ewì tí à ń perí yìí ni a fún ẹ̀yà àkọsílẹ̀ kan tí a máa ń fi ohùn dídùn kà Aladi gbà pé ewì jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí àwọn ènìyàn ń gbà fi èrò ọ̀kan wọn hàn nígbà tí Akinjọgbin fi òǹtẹ̀ àkọsílẹ̀ lu ewì ó sọ pé Ewì ni orúkọ àjúmọ̀jẹ́ tí a fún ẹ̀yà àkọsílẹ̀ kan tí a máa ń fi ohun dídùn sọ tí a sí máa ń fi ohùn dídùn kà Ó tẹ̀síwàjú láti fún ewì lóríkì mìíràn lójú ewé kẹkànán ó ni ewì ní ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ lórí ohunkóhun tí ó bá ti inú ẹní wá tí ó jẹni lọ́kàn tí ó sì mú ni lára tí a sọ tàbí tí a kọ lọ́nà tí ó mú ni lọ́kàn tí èdè rẹ̀ sí dùn ju bí a ti ṣe ísọ ọ̀rọ̀ lásán lọ Irú ewì báyìí lè jẹ́ lórí nǹkan ayọ̀ bí i owóníní ìgbéyàwó ìkómọ ìgbéga Ó lè jẹ́ lórí nǹkan ìbànújẹ́ bí òfò ọfọ̀ àrùn ìjàmbá Ó lè jẹ́ lórí ìhùwàsí ènìyàn bí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ìgbéraga àríyá ọ̀yàyà inú ṣíṣọ́ ìkàṣíṣe ìkórira ìfẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sọ pé ewì dúró gẹ́gẹ́ bí i dígí tí ń fi àwòrán ohun tí ó lé ṣẹlẹ̀ tàbí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé tàbí ohun tó yẹ kó ṣẹlẹ̀ hàn wá àti pé kì í ṣe dandan pé ohun tó ti ṣẹlẹ̀ tàbí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ nìkan ni ewì ń fi hàn wá Ó jẹ́ kí ó yé wa pé Bùfúnminbùfúnọ ni ọ̀rọ̀ akéwì àti àwùjọ bí àwùjọ ṣe ń ran akéwì náà ni akéwì ń ran àwùjọ Bí ewì ṣe jẹ́ bí dígí tí a fi ń wo àwùjọ bẹ́ẹ̀ náà ni yóò tún jẹ́ kí a mọ ìhà tí akéwì kọ sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń gbé sáyé Ó lè lòdì sí i ó lè fara mọ́ ọn ó sì lè dábàá àtúnṣe Bákan náà Ọdúnjọ sọ pé ewì ni ohun tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì pè ni ní èdè wà ni àwa Yorùbá ń pé ní aròfọ̀ a tún lè pé é ní ewì tàbí iwì ó tẹ̀síwàjú láti sọ pé ewì dúró gẹ́gẹ́ bí i kókó àrògún tí àgbékalẹ̀ lọ́nà tó lẹ́wà pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ tó lẹ́wà létí àti lẹ́nu ó gbà e ẹ̀bùn ní ewì kíké Ó jẹ́ kí ó yẹ̀ wa pé ẹ̀bùn láti òkè wá ni ewì jẹ́ nítorí pé Ọlọ́run ni ó ma ń dì ìdí fún ènìyàn ni ohun tí yóò fi gbé ewì jáde kì ó tó le lẹ́wà létí tàbí lẹ́nu àti lójú àwọn olúgbọ́ tí yóò kẹ́tí lẹ́yìn nígbà tí ó wí pé ewì ni à ń lò láti tọ́kasí àwọn Ohun ẹnu Yorùbá tí a ń gbé kalẹ̀ lóhùn ẹnu lọ́nà bí i kíké bí orin tàbí lọ́nà tó sún mọ́ ohun tí a fi ń sọ̀rọ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà èdè inú wọn tayọ ọ̀rọ̀ gbẹrẹfu Ó tẹ̀ síwájú láti sọ pé ewì kan náà la pè àwọn ìjìnlẹ̀ ohun ẹnu tí a kọ sílẹ̀ tí a sì ń ké Èyí ni wí pé òǹkọ̀wé tàbí akéwì gbọdọ̀ jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ àgbà ti yóò mo àpadé àti àludé èdè di jú kí a tó lè pé é ni akéwì Nítorí ewì kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣákálá tí ó ní ooru ẹnu Ní ti Ọ̀pádọ̀tun sọ pé ewì jẹ́ àkójọpọ̀ àṣàyàn ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ tí a máa ń fi ohun dídún ké lọ́pọ̀ ìgbà tí ó sì máa ní ìgbóhùnsókèsódò ní òpin gbólóhùn àti lórí ẹyọ ọ̀rọ̀ pàtàkì bákan náà sí ni onírúurú ọ̀nà èdè máa ń tawọ́ tasẹ̀ nínú rẹ̀ Èyí ni pé bí a bá wo inú ewì a o rí pé akéwì mọ̀ọ́mọ̀ tó ìgbohùn sókè sílẹ̀ ni ọ̀nà tí ó fi wuyì gidigidi ni Ọpẹ́ fẹ̀yìntìmí wo ewì gẹ́gẹ́ bí ìjìnlẹ̀ ìlò èdè tí a ṣábà máa ń fi gbólóhùn kékeré ṣẹ̀dá tó ń pòju nínú wà tí a rán níṣẹ́ ara ọ̀tọ̀ òun ni ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jùlọ ti ẹ̀dá ń gbà gbé èrò ọ̀kan wọn jáde Èyí fihàn pé èdè ni irinṣẹ́ àtinúdá àtinúrò pẹ̀lú gbólóhùn tí ó kéré jọọjọ láti fi ṣẹ̀dá ewì yálà nípa kíkọ́ tàbí èyí tí a sọ tàbí ké Ìwé atúmọ̀ èdè tí a mọ̀ sí Ó kì í ewì báyìí pé Ewì ni ohun tí ó bá lè múniromú jinlẹ̀ nípa ìlò èdè rẹ̀ tí a ṣètò lọ́nà kan pàtó tó múnilára nípa ìtumọ̀ ohun dídùn àti ìwọ́hùn Èyí ní wí pé ohun tí a bá máa pé ni ewì gbọdọ̀ jẹ ohun tí ìlòèdè rẹ̀ yàtọ̀ sí èdè ojoojúmọ́ tí yóò farasin Nítorí ẹní tí yóò ba ké ewì gbọdọ̀ jẹ́ ẹní tí o mọ bí a ṣe ń lọ ẹ̀dọ̀ kí ọ̀rọ̀ nítorí pé bí eléégún bá ń pẹ̀sà tí o ní ìjálá ń sun ìjálá tàbí tí wọ́n ba ń ṣeré ọdẹ arí pé àwọn èròǹjà tí wọ́n fi ń gbé ewì wọn kalẹ̀ máa ń wọni lára ju ọ̀rọ̀ wuuru lásán lọ Èyí ni ohun tí Ọlábímtán fi sọ pé Àwọn mìíràn a máa rò pé èrò ṣákálá kan tí ẹnikẹ́ni bá fọ̀ jáde ni àròfọ̀ Kì í ń ṣe gbogbo ìgbà ni èyí fi jẹ́ òtítọ́ àròfọ̀ gidi gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ni iye lórí ní gbogbo ìgbà À ní nínú èyí tí ẹnikẹ́ni yóò rí ohun dímú ìbá ṣe ọmọdé àgbàlagbà ni àsìkò yìí tàbí ni àsìkò tí ń bọ̀ Àkíyèsí wa ni pé ewì níí ṣe pẹ̀lú ṣíṣe àgbékalẹ̀ èrò ìjìnlẹ̀ ni pa ohun kan tàbí òmíràn bẹ́ẹ̀ sí ni ìlò èdè lọ́nà ara jẹ́ ẹ́ lógún Èyí tó jẹ́ pé àṣàyàn ọ̀rọ̀ tí a mọ̀ónmọ̀ tò pọ̀ lọ́nà tí ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò fi wọni lọ́kàn tí àwọn ẹ̀dá fi gbé ẹ̀dùn ọ̀kan wọn àti èrò inú wọn jáde Fún ìdí èyí a lè fi ewì pé àkíyèsí àwọn ènìyàn sí àwọn ohun tí ó ń lọ láwùjọ Ewì tí á ń sọ̀rọ̀ yìí yàtọ̀ sí àwọn lítíréṣọ̀ àpilẹ̀kọ Yorùbá tó kù bí i ìtàn àròsọ eré oníṣe nítorí tí a bá wo ọnàèdè àti ìwọ́hùn inú ewì máa ń wọni lára ganan ju tí ìtàn àròsọ tàbí eréoníṣe lọ Bí àpẹẹrẹ nínú ọ̀rọ̀ wuruwu tó ó lọ bayiii Ng kò gbúròó ògì gígún nígbà ti ilẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ni ng kò gbúròó èbùbọ́ kíkù tàbí ọbẹ̀ ṣíṣe nígbà tí ilẹ̀ ṣú Ǹjẹ́ ebi kò ni fẹ́rẹ̀ pa enia kú ní ibí yìí báyìí ohùn yìí kan náà ni wọ́n kọ ni ewì báyìí ojúmọ́mọ́ ng kò gbọ́ poroporo odó ọ̀gànjọ́ gàn ng kò gbọ́ wọ̀ṣọ̀wọ̀ṣọ̀ kọ̀ǹkọṣọ̀ Ng kò gbọ́ ṣinrín kúnṣinkún éku mẹ́ja Àfàìmọ̀ káwo má sùn lébi àfàìmọ̀ Bí a bá fi ewì yìí wé ọ̀rọ̀ wuruwu tí ó wà lókè rẹ̀ a ó rí i pé ọ̀rọ̀ tí a lò láti fi sọ ohun ti a fẹ́ àti bí a ti ṣe lò wọ́n bí a ti ṣe ń gbé ohun sókè àti sí ìsàlẹ̀ nínú ewì dára púpọ̀ ju ti ọ̀rọ̀ sísọ lọ Tí a bá kọ ewì sí inú ìwé a kì í kọ ọ́ kún gbogbo ojú ìwé abala ojú ìwé kan ni á máa ń tò ó sí ní ẹsẹẹsẹ Ṣùgbọ́n ni ti lítíréṣọ̀ àpilẹ̀kọ Yorùbá yòókù a máa ń kọ kún ojú ìwé ní tí ó sí máa na jẹ́ ọ̀rọ̀ wuuru bí a ti ń sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ láwùjọ TÍỌ́RÌ ÌṢÀMÚLÒ ÌṢỌWỌ́LOÈDÈ Iṣẹ́ lámèyítọ́ lítíréṣọ̀ ni iṣẹ́ tó gba ìrònú àròjinlẹ̀ tó sí tún jẹmọ́ àwíjàre àti àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ tó jẹmọ́ lítíréṣọ̀ Ìdí nìyí tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan ṣe sọ ọ́ ni ṣàkátá pàrá bí ikọ́ àgbà pé Èyí ń sọ ní pàtó ohun mẹ́ta pàtàkì tí lámèyítọ́ gbọdọ̀ dojúkọ kó sí gbèṣè nínú iṣẹ́ rẹ̀ Ìkínńí ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé èkejì ni ìtumọ̀ tàbí ìtúpalẹ̀ tó gbámúsẹ Nígbà tí ẹ̀kẹta jẹ́ ìgbéléwọ̀n afọ̀ tó ń tú palẹ̀ Nítorí náà ẹní tí a bá pè ní lámèyítọ́ tí àwọn kókó mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyìí kó bá jẹyọ nínú iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ tó ṣe a jẹ́ pé iṣẹ́ àjàǹbàkù ló ṣe Èyí túmọ̀ sí pé ẹní tí a lè pé ní lámèyítọ́ ni ẹní tó lè yọ òbí kí ó sí pa àbìdun afọ̀ tó gbé ka iwájú rẹ̀ Irú afọ̀ bẹ́ẹ̀ kí báà jẹ́ ewì ìtàn àròsọ tàbí eréoníṣe ó gbọdọ̀ lè ṣe akitiyan láti fa kòmóòkun yọ láti ṣe àgbékalẹ̀ èrò tó soi mọ́ kókó mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyìí Bákan náà tíọ́rì ni òfin tàbí ìlànà kan gbòógì tí à ń tẹ̀lé ní ṣíṣe ohun kóhun ó lè jẹ́ nípa ìwé kíkọ́ ijó jíjó ìlù lílù ìwé kíkà gbígbé àwọn nǹkan tuntun jáde nípa ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ọ̀nà tàbí ti Sáyẹ́ńsì Adéyẹmí fi tíọ́rì wé abẹfẹ́lẹ́ ìmọ̀ tí a fi ń la ìfun àti ẹ̀dọ̀ iṣẹ́ lítíréṣọ̀ Ó tún sọ ọ́ síwájú pé nínú ìmọ̀ Sáyẹ́ńsì ni tíọ́rì ti jẹyọ àti pé ìwádìí yòówù ti kò bá gùnlé tíọ́rì kan pàtó kò lè gbóúnjẹ fẹ́gbẹ́ kó tún gbàwo bọ̀ Tíọ́rì ni ìlànà kan tí ó jẹ jáde láti inú ìrònújinlẹ̀ tí a kà sí òótọ́ lẹ́yìn tí a dán an wò tí ó sì jẹ́ òótọ́ bákan náà Ṣùgbọ́n tíọ́rì tí a ní lọ́kàn báyìí ni ti lítíréṣọ̀ Gẹ́gẹ́ bí àríwòye Ọbáfẹ́mi ní pa tíọ́rì lítíréṣọ̀ ó sọ pé Ohun tí Ọbáfẹ́mi ń sọ ni pé ohun èlò fún àlàyé lórí iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ni tíọ́rì Ohun èlò ìgbóye òǹkọ̀wé yọ ni gbogbo ìmọ̀ ọgbọ́n òye ìran àti ìmọ̀ọ́nṣe òǹkọ̀wé kò lè di mímọ́ fún aráyé láìsí tíọ́rì Afòyeyéni afìmọ̀kọ́ni nípa lítíréṣọ̀ ni gbogbo ohun tí òǹkọ̀wé bá sì ń fẹ́ẹ́ gbé fún aráyé abẹfẹ́lẹ́ ìmọ̀ ni yóò là á wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ Onírúurú bí aṣọ alágẹmọ ni tíọ́rì tí ó wà fún àwọn gbẹ́nugbẹ́nu láti fi ṣe ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ọnàlítíréṣọ̀ kan tàbí òmíràn Díẹ̀ lára àwọn tíọ́rì ohun nì wọ̀nyìí Tíọ́rì ìfojú ìwà ọmọlúàbí wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀ Tíọ́rì ìfojú ìhun wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀ Tíọ́rì ìfojú ààtò wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀ Tíọ́rì ìfojú ìmọ̀ ìbágbépọ̀ àwùjọ wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀ Tíọ́rì ìfojú ìmọ̀ ìtàn ìgbésí ayé òǹkọ̀wé wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Láìsí àníàní a ó rí pé gbogbo tíọ́rì yìí ni ó ní àmúyẹ àti àléébù tirẹ̀ Nítorí náà a kò lè pé tíọ́rì kan ní gbéetán nínú àwọn tíọ́rì tó wà fún iṣẹ́ àtúpalẹ̀ iṣẹ́ ọ̀nà lítíréṣọ̀ bẹ́ẹ̀ sì kò sí èyí tí a lè yọ sọnù A kò lè lo tíọ́rì kan láì lo àwọn mìíràn mọ́ọn Kò sí tíọ́rì kan tó lè rí ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè iṣẹ́ lámèyítọ́ nínú iṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn tíọ́rì wọ̀nyìí kò wúlò ṣùgbọ́n ìwúlò wọn wà lọ́wọ́ bí a ṣe lò wọ́n àti iṣẹ́ tí a lò wọ́n fún Ní ti tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè ohun dàbí ìyàwó àṣẹ̀ṣẹ̀ gbé nínú àwùjọ àwọn onímọ̀ àti ìlànà ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ lítíréṣọ̀ yòókù Nítorí náà ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè ló ṣe ìṣípayá sí oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí àwọn oníṣẹ́ ọnà ń gbà ronú tí wọ́n ń gbà lọ èdè lọ́nà tó rẹ wà Ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè ń jẹ́ kí ìwúrí wà fún iṣẹ́ ọnà Ó ń jẹ́ kí àwọn oníṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ tiraka láti rí pé iṣẹ́ wọn dára Ó máa ń tọ́ka sí àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ O tún ń jẹ́ kí ìmọ̀ nípa èdè ìmọ̀ nípa lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ nípa ẹwà lítíréṣọ̀ jinlẹ̀ sí i Oríṣìíríṣìí ni ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè tó wà díẹ̀ lára wọn kà á sí àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ O tún ń jẹ́ kí ìmọ̀ nípa èdè ìmọ̀ nípa lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ nípa ẹwà lítíréṣọ̀ jinlẹ̀ sí i Oríṣìíríṣìí ni ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè tó wà díẹ̀ lára wọn ni ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè ajẹmọ́ ìmọ̀ẹ̀dá èdè ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè ajẹmọ́ lítíréṣọ̀ tàbí aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè ìkọ́ni tàbí ajẹmọ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àti ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń kò èdè ilẹ̀ òkèèrè Ọ̀kanọ̀ọ̀jọ̀kan oríkì ní àwọn onímọ̀ ti fún ìsọ̀wọ́loèdè lára wọn ni Tí ó ki ìṣọwọ́loèdè báyìí Ohun tí sọ ni pé ìṣọwọ́lọèdè ni ṣíṣe àyẹ̀wò afọ̀ ajẹmọ́ lítíréṣọ̀ èdè pé ohun àkọ́kọ́ nínú ìtúpalẹ̀ àti kíka iṣẹ́ lítíréṣọ̀ gbọdọ̀ tẹ̀lé ìgbésẹ̀ inú ìmọ̀ ẹ̀dáèdè Ohun àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì sí wa nínú kíka lítíréṣọ̀ ni èdè inú rẹ̀ ṣàlàyé pé ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè ní í ṣe pẹ̀lú ìyapa yálà ìyapa ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ìyapa tó jẹ́ àbùdá ìṣọwọ́ kọ̀wé ẹnìkan Ó fi kún un pé a gbọdọ̀ tọ́ka sí iye ìgbà tí irúfẹ́ ìyapa yìí wáyé nínú ìṣọ tàbí iṣẹ́ ọnà tí a ń yẹ̀wò Ìgbàgbọ́ rẹ̀ ní pé síṣọ iye ìgbà tí ìyapa wáyé máa ń jẹ́ kí ìtúpalẹ̀ wá ni i ṣe pẹ̀lú Sáyẹ́ńsì tí ohun tí gbogbo wá rí yóò fi fẹ́rẹ̀ dọ́gba nínú ìwé rẹ̀ ní ìṣọwọ́loèdè jẹ́ ìmọ̀ kan tí ó ń ṣàwárí gbogbo èròjà tí a lè ṣàlàyé nínú èdè Ohun tó fún ka mọ́ ni pé ìṣọwọ́loèdè jẹ́ ọ̀nà tí a lè gbà ránṣẹ́ nínú afọ̀ nípa ṣíṣe àmúlò oríṣìí àbùdá èdè lọ́nà tí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè fi yàtọ̀ sí ìtumọ̀ tí a ti mọ mọ ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú èdè gbà pé ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè ní i ṣe pẹ̀lú ìtẹnumọ́ tó fẹ́ dàbí àfikún iṣẹ́ ọ̀nà ṣùgbọ́n tó hàn dáadáa nínú èdè tí a ń yẹ̀wò láì pa ìtumọ̀ lára Bákan náà kí èrò àwọn yòókù lẹ́yìn Ó ní Ohun tí ń sọ ni pé ìṣọwọ́loèdè ni àyẹ̀wò afọ̀ ajẹmọ́ lítíréṣọ̀ pẹ̀lú ojú ìmọ̀ ẹ̀dá èdè Ìyàtọ̀ láàrín ìmọ̀ ìṣọwọ́lọèdè àti lámèyítọ́ òun ìmọ̀ ẹ̀dá èdè ni pé ìṣọwọ́loèdè ni afárá láàrín àwọn méjèèjì Nítorí náà ohun tí a mọ̀ sí ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè nínú ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ni ṣíṣe àmúlò gbogbo ohunèlò ìmọ̀ lingusíìkì ní ìbámu pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè tí fi ẹnu kò lé lórí nínú iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Ìṣọwọ́loèdè ni ẹ̀kọ́ìmọ̀ iṣẹ́ ọnà tó sọ mọ́ yíyan àbùdá èdè tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan pàápàá jùlọ ìṣẹ̀ṣe iṣẹ́ ọ̀nà Awóyalé dá bà á òdiwọ̀n márùnún tí a lè ló láti ṣàlàyé bí ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè aṣafọ̀ ti rí nínú afọ̀ ni a máa lò Àwọn òdiwọ̀n ohun ni ìkójọpọ̀ ìṣopọ̀ ìtayọ ìṣewẹ́kú àti ìfúnnítumọ̀ Ó tẹ̀síwàjú láti sọ pé ẹ̀ẹ̀kan náà ni gbogbo àwọn òdiwọ̀n márààrún wọ̀nyí ń ṣíṣe pọ̀ lórí iṣẹ́ lítíréṣọ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wọn ló tún ni oríṣìí òfin lábẹ́ tó wà fún àti ṣàlàyé kíkún lórí òdiwọ̀n kọ̀ọ̀kan Èyí ló máa ń mú kí iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ lítíréṣọ̀ pẹ̀lú tíọ́rì ìmọ̀ ìsọ̀wọ́loèdè gún régé Kó sì kún jú òṣùwọ̀n Àtẹ àwòrán tó gbé kalẹ̀ nìyí ṣe àgbékalẹ̀ òdiwọ̀n méje tí a gbọdọ̀ wò nínú ìwé kan kí a tó lè pé ni afọ̀ Àwọn òdiwọ̀n tí wọ́n dá bàá ni ìṣopọ̀ ìṣewẹ́kú èrò ṣíseégbà iṣẹ́ jíjẹ́ ayé àsomọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ lítíréṣọ̀ mìíràn Èyí tí gbogbo rẹ̀ ṣiṣẹ́ papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ìtúpalẹ̀ ṣe àgbékalẹ̀ ẹ̀ka mẹ́rin kan ló pé ìṣọ̀rí itọsuna Ìlànà yìí kan náà ni pé ní onírúurú iṣẹ́ aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ tó jẹ mọ́ ìsọ̀rí ajẹmáfọ̀ Ìlànà mẹ́rin tó gbé kalẹ̀ ni ìkójọpọ̀ ìṣopọ̀ ìlànà iṣẹ́ tí a rán àti ìtayọ Ní ìtẹ̀síwájú a rí i pé ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ tí ó pé ni ni Awóyalé gùnlé Ó pé é ní Nínú ìgbésẹ̀ tí Awoyale là kalẹ̀ a rí àwọn ìyàtọ̀ níbi òdiwọ̀n tí ó ṣàmúlò lára ìyàtọ̀ òdiwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni ṣíseégbà isẹ́jíjẹ́ ayé èrò àti nínú àsomọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ lítíréṣọ̀ mìíràn bí àti ORÍ KẸ́TA ÌTAYỌ ÀWỌN ÈRÒJÀ INÚ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ ÌFÁÀRÀ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onímọ̀ ló ti ṣíṣe lórí ìlànà yìí lára wọn ni Awóyalé Ọlábọ̀dé Bámisílẹ̀ Àjàyí àti Ọdẹbunmi Àwóyalé ṣàlàyé ìtayọ gẹ́gẹ́ bí ara kan lára ìhun ṣe yọ tàbí rú sókè ju ara tí ó kù lọ Ó ní ìyọsókè yìí lè jẹ́ nípa fífẹ̀ ṣíṣe ṣónṣó jìn kòtò gbẹ́nusókè tàbí ga ju ara ìhun tó kù lọ Ó ní a gbọdọ̀ wo lítíréṣọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyọ ìlà kan ṣoṣo ni Ibí tí ìlà yìí bá ṣe ga ju ara wọn lọ sí ni à ń pé ní ìtayọ Bí iké kan bá ta èkejì yo a jẹ́ pé ó ta á yọ nì yẹn Èyí tó bá ṣe pàtàkì jù nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló ta àwọn yòókù rẹ̀ yọ Ohun tí ìtayọ máa ń fún wa nínú iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ni láti mọ ipò tí àwọn èròjà tó wà ni ọwọ́ kan wà sí ara wọn kí a tó mọ òtéńté ibi tó bá tayọ jù pátápátá Oríṣìíríṣìí òfin ló wà tí a lè lò láti wo ìtayọ àwọn èròjà nínú iṣẹ́ lítíréṣọ̀ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òfin yìí ló jẹ́ pé ìhà ìkọsíra àfojúrí ni a ó ti ṣe ìgbéléwọ̀n àti àmúlò wọn Lára àwọn òfin ohun ni ìfààyègbà Àwòjìnlẹ̀ ibi ìjẹyọ àti ìtẹnumọ́ Aṣafọ̀ kì í fọwọ́ kan náà mú gbogbo èròjà inú afọ̀ rẹ̀ Ó máa ń fi ààyè gba àwọn èròjà wọ̀nyìí ju ara wọn lọ a kíyèsí èyí ni pa iye ojú ìwé tí aṣafọ̀ yà sọ́tọ̀ fún èròjà kọ̀ọ̀kan Bákan náà a tún lọ iye gbólóhùn inú ewì náà láti mọ̀ bí aṣafọ̀ ṣe fi ayé gba èròjà kọ̀ọ̀kan nínú ewì Aṣọ Ìgbà Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ òǹkọ̀wé fi ayé gba àwọn kókó kan ju àwọn yòókù lọ Àwọn tí ṣàkíyèsí pé o fààyègbà jù wọ̀nyìí ló gba ìtayọ Bákan náà a tún wo ipa tí èròjà kọ̀ọ̀kan kò nínú afọ̀ Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé àfòyemọ̀ lásán ni èyí a kò fi bẹ́ẹ̀ fún wọ́ mọ́ọn Ní ṣókí gbogbo òfin tó yẹ kí a lò lá bẹ́ òdiwọ̀n ìtayọ ni a lò nínú ewì Aṣọ ìgbà Báyìí a ó wo ìtayọ àwọn èròjà gbogbo tó wà nínú ewì yìí lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan ÌTAYỌ ÀWỌN KÓKÓ INÚ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ Òfin ìfààyègbà ní a lò láti wo ìtayọ àwọn kókó inú ewì Aṣọ ìgbà A lo iye gbólóhùn tí òǹkọ̀wé fi gbé kókó kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ A tún wo iye ojú ìwé tí òǹkọ̀wé fi gbé kókó kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ pẹ̀lú àpapọ̀ iye akópa tí òǹkọ̀wé fún ní ojúṣe láti gbé kókó yẹn jáde Kókó méje pàtàkì ni a rí nínú ewì náà Nígbà tí a ṣe àtúnpín àwọn àkọlé àti àkóónú inú ewì náà Àwọn méjèèje ni ÒṢÈLÚ ÌWÀ OBÌNRIN IṢẸ́ ỌBA ÌFẸ́TỌ́DUNI Ọ̀RỌ̀ÌYÀNJÚ ÌGBÉSÍ AYÉ Ẹ̀DÁ ÀTI ÌKÌLỌ̀ ÌWÀ Nígbà tí a sí lọ òdiwọ̀n wọ̀nyí kókó tí a pè ní ìgbésí ayé ẹ̀dá ni ó gba ìtayọ Ìdí ni pé nínú kókó méje tí a rí kójọ nínú ewì náà òun ni ìgbà ìjẹyọ rẹ̀ pọ̀jù Lábẹ́ ìgbésí ayé ẹ̀dá yìí ni a ti rí ewì ipò ọlá oi Igi Kan ò Dágbò ṣe oi Tèmi ò Sòro! oi AbOlódùmarè ń Tòogbé? oi Kínin La Oṣù Wọ́n Lèyí oi àti Pákáleke oi Gbogbo àwọn ọmọ abẹ́ yìí ibikíbi tí ọ̀kan lára wọn bá ti jẹyọ Ìsọ̀rí àkọlé àti àkóónú ewì wọ̀nyí ló ṣàfihàn ìhùwàsí àti ìṣeṣí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ní àwùjọ tí a wà Bí àpẹẹrẹ nínú ewì Pákáleke oi Páká páká Kì í tán nílẹ̀ páká leke Pọnlà pọnlá Kì í kúrò loro bàtá nígbà Kọ̀ọ̀kan Ẹ̀mí kan lónìí Ẹ̀mí kan la nàán Níí ṣe tìyàwó ọ̀dẹ̀dẹ̀ tó pọkọ ẹ̀ Ilé ó gbà á Ààyè ò gbà á níí ṣe ewé Àkárà àgbà Isinmi ìsinmi isínmi Ìsinmi wẹ̀ẹ̀ Ìsinmi kì í sí fẹ́ dàá tì ń bẹ láyé Ìsinmi kì í sí fénìyàn tí ń bẹ lóókè èèpẹ̀ Ọjọ́ ikú ẹ̀dá ni sinmi wáyé Ọjọ́ ẹ̀dá lọ wàlẹ̀ àṣà ní fọkàn lélẹ̀ Ìdúró ò sí ìbẹ̀rẹ̀ ò sí Òun lọ̀rọ̀ tíí ba ẹní gbọdọ̀ mì Wàhálà tíí pẹran ọ̀jẹ Wàhálà ọ̀hún níí bí Olówó olówó nù Èyí fihàn pé nínú gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sẹ́dàá láyé pé kò sí ìsinmi fẹ́ni sí wà láyé ẹ̀yìn ikú ni ìsinmi tó wà ti gbogbo ìgbésí ayé ẹ̀dá sí rọ̀mọ́ àìbalẹ̀ ọ̀kan Bákan náà nínú kókó ọ̀rọ̀ tó gba ìtayọ yìí ni a ti rí ewì AbOlódùmarè ń Tòògbé? oi níbi yìí òǹkọ̀wé jẹ́ kí a rí oríṣìíríṣìí ìwà àwọn ọmọ ẹ̀dá aádámọ̀ tí wọ́n fi ọmọlọ́mọ sẹ́só tí o sì jẹ́ pé lèmọ́mù àti rẹ́fẹ́nì ní bàbá ìsàlẹ̀ fún àwọn oníṣẹ́ ibi gbogbo náà Bẹ́ẹ̀ náà ní ọ̀rọ̀ yìí kò yọ àwọn wòólì tí ń káyaaláya lórí òkè fún àbó irọ́ òun àgbèrè tí wọn tún ni ohun amúṣagbára lábẹ́ aṣọ Gbogbo èyí ni òǹkọ̀wé ń fi pàrọwà fún àwùjọ láti jéwọ́ nínú gbogbo ìwà ìbàjẹ́ wọ̀nyí tí ó ń gbode kan Bí àpẹẹrẹ Àbí kin ni ká pé tọ̀gá iṣẹ́ tó ń bàná owó iléiṣẹ́ Bẹ́ẹ̀ pẹ́kẹ̀ kan ó gbọdọ̀ mi Ìtàkùn tó ni kẹ́rin má gòkè àlọ́ Tòun tẹrin níí lọ Ọmọsẹ́ tó bá fẹ́ yọjúràn Ọ̀ràn ní yọjú irú wọn Irú wọn i wọn sọ dòpò àgbàmọ́ná Tàbí kín ni ká pé tẹ̀dáènìyàn tó wò sùn sùn to gbọ́mọ ọlọ́mọ ó gbọ́mọ ọlọ́mọ tán ó fi sẹ́ṣó? Ó wá lówó tán ó bẹ̀rẹ̀ sí náwo yà Ó ń fowó lùkúdù tákàá ni mọ́sálásí Ó ń fowó oṣó ṣe yànyànṣe ni ṣọ́ọ̀sì Ó tí wá jẹ́ Elédùà Tọ́mọ èèyàn ó dọdẹ ẹranko mọ́ Elẹ́ran ara bí i ti wọ́n ni wọ́n pa sọnù Ewì èyí ganan tún wa jẹ́ kí a rí ọ̀pọ̀ ohun tì ń ṣẹlẹ̀ ni àsìkò tí a wà yìí tí ó jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ló sàa fẹ dí olókìkí ti gbogbo èèyàn á máa wárí fún tí wọn yóò sí máa jẹ́ lọ́tùnún oósì bí ọmọ tuntun jòjòló tàbí ìyàwó àṣẹ̀ṣẹ̀ gbé Kókó kejì tó tún pọwọ́ lé ìgbésí ayé ẹ̀dá ní òṣèlú lábẹ́ rẹ̀ ni àti rí ewì Ṣáágo ń Búgò oi Oṣù Ìṣọnu oi Òníkàn yìí Rọra oi Básabàsa oi Nínú àwọn ewì yìí òǹkọ̀wé jẹ́ kí a rí awuyewuye àti rògbòdìyàn tí ó ṣẹlẹ̀ láàrín ìjọba ológun àti ìjọba alágbádá tí o jẹ́ pé àṣà gbé àwòdì gbà á ní ọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì jẹ́ nínú ètò ìṣèlú àti iṣẹ́ ìjọba ilẹ̀ wa Bí àpẹẹrẹ ewì Ṣáágo ń Búgò oi Alágbàá ń bàná owó bó ti fẹ́ Alágbàá ń fajẹ́ ṣòfò láì wẹ̀yìn wò Alágbàá yá bùtùlú tán Sebi ẹ̀sùn ńlá lalágbàá fi kan alágbádá P álágbádá ò mọlé tò Àṣẹ késekése ń tayé Alágbádá Ta ni kò ṣàìmọ̀ Páṣàá gbé e Àwòdi tún fò fẹ́rẹ̀ gbàá lọ̀rọ̀ Ọ̀rọ̀ ọ̀hún ń kọ́? Kò ṣé ṣáágo tì ń búgò Kókó kẹ́ta lábẹ́ ìtayọ ni ìwà obìnrin Lábẹ́ rẹ̀ ni a ti rí oríṣìíríṣìí ìwà burúkú gbogbo ló kún ọwọ́ obìnrin ìbáṣe ọmọdébìnrin tàbí àgbà obìnrin tí ó sí tí di ohun ẹ̀sọ́ àti aṣọ ìyìn láwùjọ wa Lábẹ́ ìwà obìnrin ni a ti rí ewì wọ̀nyí Orogún oi Èlẹ̀ Òṣíẹlẹ̀ oi Lẹtà sí Ẹwà oi àti Sisí Akadá oi Lára ohun tí ewì yìí tẹnumọ́ tàbí tí òǹkọ̀wé fẹ́ kí a mọ̀ ni pé talẹ́ lójú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin pàápàá jùlọ ọmọge O ṣe àfihàn èyí nínú ewì Lẹtà sí Ẹwà oi ó ní Ẹwà mi ọ̀wọ́n Àánú rẹ ṣe mi jọjọ O gbẹ́rù kan àrà tó lóòrìn rù Ẹrù ìbànújẹ́ ayé lẹrù òun Tí mo rí ketekete Gbogbo ọkùnrin lo ó ń sọ̀rọ̀ Tínú rẹ ń dùn sìnsìn Ọ̀gọ̀rọ̀ ọkùnrin ló ń dúró wò ọ́ Tìkátẹ̀gbin níí pópó Bí wọn bá ti pàdé rẹ Lára àwọn ọdájú kùnrin bàyàkókóìnàkí Tó kọnu ìfẹ́ sí ọ Dípò kió o yankọ gíríkì mímú lo ń m ọkùnrin lámùù jùúlẹ̀ Dín fùlẹngẹ fùlẹngẹ kù sinmi à ń ṣe yànyàn ǹṣe Kọ́lá ara rẹ tó sí lọ kẹ́wà ara rẹ̀ tó wọ̀kùn Ìwà ni ó lò mà lẹwà Kókó kẹ́rin nínú ewì Aṣọ ìgbà ni ìkìlọ̀ ìwà èyí ni ọ̀rọ̀ ìṣítí tí òǹkọ̀wé kọ sí gbogbo ọmọ ẹ̀dá ènìyàn láwùjọ pé ìwà ṣe kókó fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí òwe àwọn àgbà pé obìnrin sọ̀wànù ó lóhun ó rí ilé ọkọ gbé Nítorí náà ẹní tí yóò ba débi gíga tàbí bá àgbà jẹun ó gbọdọ̀ tọ́jú ìwà rẹ̀ nítorí ohun ni ẹ̀sọ́ ènìyàn Lábẹ́ kókó ọ̀rọ̀ yìí ni a ti rí ewì Ẹ̀yìnlàáró oi Gbéborùn oi Àgbà kù Jàńbá Ṣèlú oi àti Kìninla Oṣù wo Lèyí? oi A ó wo àpẹẹrẹ nínú ewì Ẹ̀yìnlàárò láti fìdí kókó yìí múlẹ̀ ó ní ká ronú kátó ṣohun kóhun Ìbá ṣèwọ ìbá ṣèmi Táa bá fẹ̀gbin lọ̀ ọ́ Iwọ jẹ́ gbà bí? Ó yẹ kágbàlagbà ronú jinlẹ̀ Kó má yòkú rorò sọ́mọdé Kó máa rántí pé màjèsín ó ní ń bọ̀ wá dàgbà báun ìwọ àwé tó jólorí tó o jẹ aṣáájú tó ó dẹni àpésìn bí òkèbàdàn má ṣe jayé àjẹ dàlú ma ṣe gùnlé ìwà ìkà kò sí ohun tẹ́dàá ṣe tí kò ni kẹ́san ó bá rẹ̀yìn ọ̀rọ̀ wò ọ̀rẹ́ kò tó ṣohunkóhun Ẹ̀dá tó wẹ̀yìn ọ̀rọ̀ kì í sì wà hù Èyìnlàárò ajá ọdẹ Kókó karùnún ní ọ̀rọ̀ ìyànjú èyí ti ó sí ní àwọn kókó kékèké lábẹ́ rẹ̀ bí kábíyèsí oi Igi Kan ò Dágbóṣe oi orí jẹ́ ń lọ́tàá oi àti Imúníkà oi oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ ìyànjú ni òǹkọ̀wé jẹ́ kí a mọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń lo láwùjọ tí a wà yìí tí o sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹní ìkà ní a kò lè rí tí ó jẹ́ pé wọ́n kì í ṣe ènìyàn tí wọ́n kàn dasọ ènìyàn bora lásán lásán òǹkọ̀wé fi ẹ̀rí èyí múlẹ̀ nínú ewì tí ó ń pé àkọlé rẹ̀ ni Imúníkà Ó sọ báyìí Kò sóòórùn tímú ò gbọ́ Bó tí ń gbóòórùn àdídùn Bẹ́ẹ̀ nímú ń gbọ́ tóbu Bí wọn ń dínbẹ̀ lọ́nà tó jìn kí á nínú gbé e Bẹ́nìkan túṣọ yẹ́ẹ́ kí á mọ́sá nínú ṣòfófó Bímú ti wá gbóòórùn tó imú kò gbóòórùn abínú ẹní Imú rí kánńbó lásán ni kò le è ṣàfihàn ìkà èèyàn Bímú bá mọ ṣẹ́ ẹ̀ dọ́ba Òréré là bá ti yẹra fólúbi Bímú ba fínlẹ̀ bọ́ ti tọ́ À bá ti pàdé ìkà èèyàn Èyí ni wí pé ó sọ̀rọ̀ gidigidi láti mọ aṣebi nítorí náà kí olúkúlùkù máa ṣọ́ra ṣe nínú ohun gbogbo àti nibikíbi tí èèyàn bá wà lókè eépẹ̀ Nítorí náà ó dára kí òní kálukú mọnú ara rẹ̀ Kókó kẹfà ni Iṣẹ́ Ọba kókó yìí da lórí ohun tí o má a ń ṣẹlẹ̀ láàrín agbaniṣíṣẹ́ àti àwọn òṣìṣẹ́ àti bí olúkúlùkù ṣe mú iṣẹ́ yìí lọ́kùnkúndùn àti ìhà ti ìjọba àti àwùjọ kọ sí àwọn oníṣe ìjọba pàápàá jùlọ iṣẹ́ tíṣà ní orílẹ̀ èdè wa lápapọ̀ Nínú kókó iṣẹ́ ọba a rí kókó ló jẹ́ ọmọ abẹ́ rẹ̀ bí mẹ́ta àwọn ni Bí iṣẹ́ tí ṣà kọ́ oi Ásù Fọnmú oi àti Olùkọ́ Èdè Òṣíẹ̀lẹ̀ oi Àpẹẹrẹ ewì tí o fi ẹ̀rí yìí múlẹ̀ gidi ni Bí Iṣẹ́ Tíṣà Kọ́ Bá a ba ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ òòjọ́ ó lójú iṣẹ́ tà á ń wí bí iṣẹ́ tíṣà kọ́ là ń sọ iṣẹ́ tí tjá tẹran ń ṣe à tẹni kọ́ṣẹ́ olùkọ́ À tẹni tí kò nímọ̀ nípa iṣẹ́ tíṣà Gbogbo wọn ni wọ́n luṣẹ́ olùkọ́ pa ihí fọwọ́ yẹpẹpẹ múṣẹ́ tíṣà Bí gbogbo oníṣe ọba gbowó oṣù lásìkò Ti gbogbo òṣìṣẹ́ ọba sí gbowó ọ̀yà lásìkò tó tọ́ kò sẹ́ni tí rántí owó iṣẹ́ olùkọ́ kò sí tíṣà tó lè máa náwó yà kò ṣẹ́sùnún mìíràn fún tiṣà lẹ́yìn àpò iṣẹ́ aláìlọ́pé niṣẹ́ tíṣà kò burú ká sọ fáláṣẹ́ kò léèwọ̀ ka wí fún ìjọba kí wọn múyì báṣẹ́ olùkọ́ kí wọn sanwó ọ̀yà olùkọ́ lásìkò tó tọ́ kí wọ́n sanwó àjẹmọ́nú lásìkò tó yẹ káyé yé rò péṣẹ́ aláìlérè niṣẹ́ tíṣà Kókó keje ní ìfẹ́tọ́duni òhun ló sì gbẹ̀yìn nínú kókó tí à ń lò Lábẹ́ kókó yìí ni a ti rí bí àwọn ìjọba àti olórí láwùjọ wa ṣe ń fi ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn dun wọ́n ti wọ́n o sì fún wọn ni ohun tótọ́ sí wọn lásìkò tótọ́ Bí àpẹẹrẹ nínú ewì Ásù Fọnmú oi Àgbáríjọpọ̀ àsù rójú ìjà ní la ṣa Wọ́n pàyanṣẹ́lódì ti Wọ́n jámi lórí àìṣiṣẹ́ ọba Àmọ́ kójú oṣù mẹ́fà ó tó pé Ọ̀pọ̀ akadá ló tí mọ́nà iṣẹ́ mìíràn pọ̀n Awuyewuye ìyanṣẹ́lédì lọ Ìjọba ṣojú fúrukò dún pọ́bọ́ débí yóò gbin Bóyá làwọn gíwá fásítí kan Fọ̀rọ̀ rora wọn wò sèbí bá a ranni níṣẹ́ ẹrú À sí fi tọmọ jẹ́ ẹ Lálá tó sí ròkè ń kọ́ ṣebí ilẹ̀ lọ ń bọ̀? Òǹkọ̀wé fi ìdí kókó yìí múlẹ̀ látàrí àti mọ ìṣeṣí àti ìhùwàsí àwọn ènìyàn àwùjọ ṣe rí tí wọ́n yóò sí máa ń gbésẹ̀ lé ẹ̀tọ́ tí ó yẹ wọ́n Lábẹ́ kókó yìí náà ni a ti rí iṣẹ́ tíṣà kọ́ oi Ògo ni Àbófo ni? oi Nítorí náà láì fọ̀pá pọ̀lọ̀pọlọ pejò a ó ṣàmúlò àtẹ ìsàlẹ̀ yìí láti ṣàlàyé kókó ọ̀rọ̀ tó gba ìtayọ nínú àwọn kókó méjèèjè ÀTẸ ÌTAYỌ KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ Kókó ọ̀rọ̀ Iyeojúìwé Iyé akópa Àpapọ̀ iye gbólóhùn Àròpọ̀ ÌGBÉSÍ AYÉ Ẹ̀DÁ Ipò ọla Igi kan ó dá gbó ṣe Tèmi ó sọ̀rọ̀ Ào Olódùmarè ń tòògbé kínin la oṣù wo lèyí Pákáleke ÌṢÈLÚ Ṣáágo ń Búgò Oṣù ìsọnu Oníkàn yìí rọra BasaBàsa Ìwà Obìnrin Orogún Ẹ̀lẹ̀ òṣíẹ̀lẹ̀ Lẹ́tà sí ẹwà Sisí Akadá ÌKÌLỌ̀ ÌWÀ Ẹ̀yìnlàáró Gbéborùn Àgbà kù jàǹbá ṣèlú Kinìnla oṣù wo lèyí Ọ̀RỌ̀ ÌYÀNJÚ Igi kan ò dágbóṣe Orí jẹ ń lọ́tàá Imú níkà Kábíyèsí IṢẸ́ ỌBA Bí iṣẹ́ tíeṣà kọ́ Asù fọn mú Olùkọ́ èdè òṣíẹ̀lẹ̀ ÌFẸ́TỌ́DUNI Bí iṣẹ́ tíṣà kọ́ Asù fọnmú Ògo nì àbọ̀ fo ni? Àtẹ yìí fihàn pé ìgbésíayé ẹ̀dá ló gba ìtayọ jùlọ pẹ̀lú iye ojú ìwé ti òǹkọ̀wé fi gba ewì kọ̀ọ̀kan Iye akópa tí òǹkọ̀wé fi gbé kókó rẹ̀ kalẹ̀ àti iyé gbólóhùn tí òǹkọ̀wé ṣàmúlò láti fi kókó rẹ̀ hàn kókó to gba ìtayọ jẹyọ ní ọ̀nà ọ̀tàlélúgbaólémẹ́jọ nígbà ti òṣèlú to pọwọ́ le jẹ́ igbaléeéjìdínàádọ́ta kókó mìíràn tó tún pọwọ́ lé ìṣèlú ni ìwà obìnrin tí ó jẹ́ igbalemọ́kànlá Lẹ́yìn rẹ̀ ni ìkìlọ̀ ìwà ti ó jẹ́ ìgbà ọ̀rọ̀ ìyànjú tó jẹ́ igbadínmẹ́ta tẹ̀lé èyí tó tún tẹ̀lé ni iṣẹ́ ọba tí ó jẹ́ ìgbà dínmẹ́wàá èyí tí ó wá gbẹ̀yìn nínú kókó ọ̀rọ̀ ni ìfẹ́tọ́duni tó jẹ́ àádọ̀sánándín méjì Látàrí àtúnṣe tí a ṣe láti pín àwọn kókó inú ìwé ewì Aṣọ ìgbà sí ìsọ̀rí ìsọ̀rí kí a tó lè fa kókó ọ̀rọ̀ to tayọ jáde a ṣe àtúntò àwọn àkọlé tí òǹkọ̀wé fún ewì kọ̀ọ̀kan nípa fífi wọ́n sí abẹ́ kókó tí ó yẹ kí wọ́n wa tí gbogbo rẹ̀ sí wọnú ara wọn bí àlùbọ́sà láwẹ̀láwẹ́ ÌTAYỌ ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ INÚ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ Ìṣẹ̀lẹ̀ ní a lè tọ́kasí bí ìtàn tó gbé afọ̀ ró Orí rẹ̀ ni a máa hun èdè lé bí ẹní ọ̀rẹ́ Kí ó ba à le rọrùn fún wa láti lè mọ ìṣẹ̀lẹ̀ tó tayọ àwọn yòókù Òfin ìfààyègbà náà ní a lò pẹ̀lú iye ìjẹyọ A wo àpapọ̀ iye akópa iye gbólóhùn lápapọ̀ àti iye ojú ìwé tí òǹkọ̀wé fi gbé ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ A rí ìṣẹ̀lẹ̀ márùnún fàyọ nínú ewì Aṣọ ìgbà Ìṣẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́ ni Ṣáágo ń Búgò oi ìṣẹ̀lẹ̀ kejì ni ewì tí òǹkọ̀wé pé àkọlé rẹ̀ ní Bí iṣẹ́ tíṣà kọ́ oi ìṣẹ̀lẹ̀ tí o sí kẹ́ta ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó dá lórí Ẹ̀lẹ̀ Òṣíẹ̀lẹ̀ oi ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó sí kẹ́rin ni ìṣẹ̀lẹ̀ lórí Lẹ́tà sí Ẹwà oi ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó sì karùnún ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó jẹyọ nínú ewì Oníkàn yìí Rọra Nígbà tí a lọ òfin ìfààyègbà iye akópa àti iye ojúìwé pẹ̀lú iye gbólóhùn Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó hàn nínú ewì Oníkàn yìí Rọra ni ó gba ìtayọ àkọ́kọ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ inú ewì Lẹ́tà sí Ẹwà ni ó gba ìtayọ ṣìkejì nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ inú ewì Bí Iṣẹ́ Tíṣà Kọ́ ni ó gba ìtayọ ṣìkẹ́ta nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ inú ewì Ṣáágo ń Búgò ni ó gba ìtayọ ṣìkẹ́rin nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ inú ewì Ẹ̀lẹ̀ Òṣìẹ̀lẹ̀ ló gba ìtayọ sí karùnún Làá fi àsìkò ṣòfò a ó lo àtẹ ìsàlẹ̀ yìí láti ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó gba ìtayọ jùlọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ márùnún ÀTẸ ÌTAYỌ ÌṢẸ̀LẸ̀ Olú Ìṣẹ̀lẹ̀ Ọmọ Abẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Iye akópa Iye ojúìwé Iye Gbólóhùn Oníkàn yìí Rọra Sànnìnú yìí sánjú Kedú takú òun ò ṣàṣepọ̀ mọ́ Ojú àánú ìran ọmọ akú fọ Lẹ́tà sí Ẹwà Ìtàn Bẹ́wàjí Wọ́n já Bẹ́wàjí lẹ̀ Bí Iṣẹ́ Tíṣà kọ́ Iṣẹ́ òòjọ́ Ìlú fọwọ́ yẹpẹrẹ múṣẹ́ tíṣà Rò ṣẹ́ni tó kọrin rẹ̀ kí tíṣà Ṣáágo ń Búgò Agbádá yìí dandè Alágbàá kò rántí ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ Ẹ̀lẹ̀ Òsíẹ̀lẹ̀ Ẹ̀lẹ̀ ti fì kánjú bọjọ́ alẹ́jẹ́ Pẹ̀lú àtẹ òkè yìí ìṣẹ̀lẹ̀ inú ewì oníkàn yìí rọra ló gba ìtayọ jùlọ pẹ̀lú iye gbólóhùn ọgọ́rùn-únlémẹ́fà iye akópa mẹ́ẹ̀dógún pẹ̀lú ojú ìwé mẹ́tadínlogún Lẹ́yìn èyí ni a rí ewì tí o sọ ìṣẹ̀lẹ̀ lẹ́tà sí ẹwà pẹ̀lú iye gbólóhùn ẹẹ́tàdínlọ́gọ́rin iye akópa mẹ́fà pẹ̀lú ojúìwé mẹ́sànán Ìtayọ inú ewì ti ìṣẹ̀lẹ̀ kẹ́ta Bí iṣẹ́ tìṣa kọ ni gbólóhùn méjìléláàdọ́ta iye akópa jẹ́ mẹ́sànán iyeojúìwé jẹ mẹ́fà Ìṣẹ̀lẹ̀ ewì ṣáágo ń búgò jẹ́ gbólóhùn o ọ̀kandínlógójì iye akópa jẹ́ mẹ́rinin iye ojúìwé jẹ́ mẹ́rinin Nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ inú ewì Ẹ̀lẹ̀ òṣíẹ̀lẹ̀ jẹ gbólóhùn mẹ́rìnlá iye akópa jẹ́ mẹ́ta iye ojúìwé sí jẹ́ ẹyọ kan Ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ ni pé a rí ìṣẹ̀lẹ̀ inú ewì oníkàn yìí rọra gẹ́gẹ́ bí èyí tó ní ìrúke ju àwọn yòókù lọ Nítorí pé ohun ni òǹkọ̀wé fààyègbà jùlọ tí o sì jẹ́ orí ÌTAYỌ AKÓPA INÚ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ ÌFÁÀRÀ Ọ̀rọ̀ nípa akópa ṣe kókó nínú iṣẹ́ ọ̀nà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ Àwọn akópa ti òǹkọ̀wé ṣẹ̀dá ni yóò ṣàmúlò nínú onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ tí òǹkọ̀wé ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ nínú lítíréṣọ̀ tí ó bá ń kọ Gẹ́gẹ́ bí àríwòye Olúyẹ́misí Adébọ̀wálé ṣe sọ ó ní àwọn ẹ̀dá ìtàn ni òǹkọ̀wé yóò fi ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu àwọn ni yóò máa lọ tí yóò máa bọ̀ nínú àwùjọ Àwọn ẹ̀dá ìtàn wọ̀nyí ni kò sí lájọ àjọ ò kún Orí wọn ni ìtàn inú ewì eréonítàn àti àròsọ máa ń dálé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin Ògúnṣínà pín àwọn ẹ̀dá ìtàn tàbí akópa sí ọ̀nà mẹ́ta àwọn ni olú edea ìtàn olú akópa ìsọ̀ǹgbè ẹ̀dá ìtàn ìsọ̀ǹgbè akópa àti ṣárépẹgbẹ́ ẹ̀dá ìtàn ṣárépẹgbẹ́ akópa Àkíyèsí wa nínú ewì Aṣọ ìgbà jẹ́ kí ó di mímọ́ fún wa pé àwọn akópa inú ewì náà yàtọ̀ sí ara wọn pedegbe nítorí akópa tí ó wà nínú ewì kìíní kọ́ ni ó wà nínú ewì kejì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Nítorí náà a ó ṣàyẹ̀wò ìtayọ àwọn akópa ewì náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹyọ nínú ewì náà Láti wá mọ ẹ̀dá ìtàn tó tayọ àwọn yòókù nínú ewì Aṣọ ìgbà a lọ òfin ìfààyègbà àti ìgbà ìjẹyọ iye ojúìwé iye gbólóhùn ni a lò fún òdiwọ̀n ìfààyègbè Nínú ewì Ẹ̀yìnlàáró àwọn akópa tí o wà níbẹ̀ jẹ́ mẹ́ta aṣáájú jẹyọ nígbà mẹ́ẹ̀dóógún pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́wàá ó gba ojú ìwé mẹ́ta òhun ní ó gbà ìtayọ akópa Nígbà tí akópa kejì ọmọdé jẹyọ nígbà márùnún pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́ta ó gba ojú ìwé méjì Akópa tó sí kẹ́ta ni akẹ́kọ̀ọ́ ó jẹyọ nígbà mẹ́ta pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́ta ó gba ojú ìwé kan Bákan náà ewì Gbéborùn a rí akópa mẹ́rinin Mòrìíyínà Límọ́tà ọkọ àti ọmọ Moríìyínà jẹyọ nígbà ogún pẹ̀lú gbólóhùn mọ́kànlá ó gba ojú ìwé méjì Límọ́tà jẹyọ nígbà mẹ́ta pẹ̀lú gbólóhùn méjì ó gba ojú ìwé kan Ọkọ jẹyọ nígbà méjì kò sọ gbólóhùn kankan ó gba ojú ìwé kan Ọmọ jẹyọ nígbà mẹ́ta ó sọ gbólóhùn kan ó gba ojú ìwé kan Nínú ewì yìí akópa tó gba ìtayọ ni moríìyínà Síwájú sí i nínú ewì Ṣáágo Ń Búgò A rí akópa méjì alágbàá àti alágbádá Alágbádá jẹyọ nígbà eẹ́rìndínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́ẹ̀dógún ó gba ojú ìwé méjì Alágbàá jẹyọ nígbà mẹ́ẹ̀ríndínlógún pẹ̀lú gbólóhùn méjìlá ó gba ojú ìwé méjì àbọ̀ Nínú ewì Orogún àwọn akópa jẹ́ mẹ́rin in òrìṣà obìnrin orogún ọkọ àti ọmọ Òrìṣà jẹyọ nígbà méjìlá pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́jọ ó gba ojú ìwé kan obìnrin jẹyọ nígbà aárùndínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́ẹ̀dógún ó gba ojú ìwé mẹ́ta Ọkọ jẹyọ nígbà márùnún pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́ta ó gba ojú ìwé méjì ọmọ jẹyọ nígbà méjì kò sọ gbólóhùn kankan ó gba ojú ìwé kan Nínú ewì Orí jẹ́ ń Lọ́tàá àwọn akópa mẹ́ta tówà níbẹ̀ ọ̀tá akadá àti olówó ọ̀tá jẹyọ nígbà ẹẹ́tàlélọgbọ̀n pẹ̀lú gbólóhùn oògùn ó gba ojú ìwé mẹ́ta Akadá jẹyọ nígbà mẹ́fà pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́rinin ó gba ojú ìwé kan Olówó jẹyọ nígbà mẹ́ta ó sọ gbólóhùn kan ó gba ojú ìwé kan Nínú ewì Lẹ́tà sí Ẹwà a rí akópa mẹ́rin ẹwà Alóyinlétè Bẹ́wàjí àti Alotònìí Ẹwà jẹyọ nígbà mẹ́wàá ó sọ gbólóhùn márùnún ó gba ojú ìwé mẹ́ta Àlòyínlétè jẹyọ nígbà méjì ó gba ojú ìwé kan Bẹ́wàjí gba ojú ìwé mẹ́ta ó jẹyọ nígbà mẹ́rinlélógún pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́rìnlá Alotònìí jẹyọ nígbà mẹ́ta ó gba ojú ìwé kan Bákan náà nínú ewì Oníkàn yìí Rọra akópa mẹ́ta wà níbẹ̀ saninu kedú Ákú Saninu jẹyọ nígbà méjìdínlógún ó gba ojú ìwé mẹ́fà sọ gbólóhùn mẹ́wàá kedú jẹyọ nígbà mẹ́sànán ó gba ojúìwé méje pẹ̀lú gbólóhùn márùnún Àkú jẹyọ ìgbà mẹ́wàá pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́fà ó gba ojú ìwé méje Bákan náà nínú ewì Kábíyèsí akópa mẹ́fà ló wà níbẹ̀ ọba ológun wèrè Adẹ́tẹ̀ Ajá èsúrú Ọba jẹyọ nígbà mẹ́ẹ̀dógún ó gba ojúìwé méjì pẹ̀lú gbólóhùn márùnún ológun jẹyọ nígbà mẹ́ta ó gba ojúìwé kan Were Adẹ́tẹ̀ Aja esuru jẹyọ nígbà kọ̀ọ̀kan lójú ìwé kan A ó lọ àtẹ ìsàlẹ̀ yìí láti ṣàlàyé àwọn ewì wọ̀nyí pẹ̀lú akópa tó gba ìtayọ nínú wọ́n lápapọ̀ ÀTẸ ÌTAYỌ AKÓPA Àkọlé ewì Ìtayọ akópa Iye ìjẹyọ Iye gbólóhùn Iye ojú ìwé Ẹ̀yìnlàáró Aṣáájú Gbébòrùn Mòrìíyínà Ṣáágo ń búgò Alágbádá Orogún Obìnrin Orí jẹ́ ń lọ́tàá Ota Lẹ́tà sí ẹwà Bẹ́wàjí Oníkàn yìí rọra Saninu Kábíyèsí Ọba Bí a bá wo ewì náà dáadáa a ó rí i pé akópa karùnún nínú àtẹ òkè yìí ló gba ìtayọ tí ó ju àwọn yókù lọ Òhun náà ni ọ̀tá èyí ni pé nínú gbogbo akópa tí a rí ohun ló ní ìjẹyọ tí ó gaju àwọn ìyókù lọ ẹní tí ó tẹ̀lé ní obìnrin tí ó jẹyọ ní ìgbà ẹẹ̀rìndínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́ẹ̀dógún ó gba ojú ìwé kẹ́ta akópa tó pọwọ́lé ni akópa kẹ́ta Alágbádá ó jẹyọ ni ìgbà ẹẹ̀rìndínlọ́gọ̀n pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́ẹ̀dógún ó gba ojúìwé méjì akópa tí ó tẹ̀lé ni Bẹ́wàjí ó jẹyọ nígbà ẹẹ́rìnlólógún pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́rìnlá ojú ìwé mẹ́ta Òmíràn in saninu ó jẹyọ nígbà méjìdínlógún pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́wàá ojúìwé mẹ́fà akópa to tẹ̀lé ni mòrìíyínà ó jẹyọ nígbà ogún pẹ̀lú gbólóhùn mọ́kànlá ojú ìwé méjì Akópa lọ tẹ̀lé e ni aṣáájú ó jẹyọ lọ́nà mẹ́ẹ̀dógún pẹ̀lú gbólóhùn mẹ́wàá ojú ìwé mẹ́ta Èyí ti o wa jẹyọ gbẹ̀yìn ni ọba ó jẹyọ lọ́nà mẹ́ẹ̀dógún pẹ̀lú gbólóhùn márùnún ojúìwé méjì Nípasẹ̀ èyí ni a fi mọ akópa tó ni ìtayọ ju nínú gbogbo wọn ÌTAYỌ ÀWỌN WÚNRẸ̀N ÈDÈ ÌFÁÀRÀ rí èdè gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn kan pàtàkì tí ènìyàn ní láti bá ra wọn sọ̀rọ̀ Èdè yìí i náà ni atọ́nà fún iṣẹ́ ọ̀nà lítíréṣọ̀ òhun ni odò fún iṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ òhun náà sì ni okùn tó sọ aṣafọ̀ mọ́ òǹkọ̀wé tàbí olùgbọ́ Nítorí ìdí èyí bí a kò bá fi ti Òjó Pe Àìná a ó rí i pé ó ṣe pàtàkì fún wa láti yẹ èdè tí òǹkọ̀wé ṣàmúlò láti ránṣẹ́ sí àwùjọ ÌTAYỌ WÚNRẸ̀NÈDÈ INÚ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ Nínú ewì yìí òǹkọ̀wé kò ṣàì ṣe àmúlò àwọn wúnrẹ̀nèdè tí ó gbé ewì náà yọ tí ó sí lẹ́wà A rí í pé àwọn wúnrẹ̀nèdè kan ta àwọn yòókù yọ Èyí ni pé òǹkọ̀wé fi ààyè gba àwọn wúnrẹ̀nèdè kan ju òmíràn lọ Ọ̀nà méjì ni a gbà láti wo ìtayọ àwọn wúnrẹ̀n èdè inú ewì yìí a wo wúnrẹ̀nèdè lórí gbólóhùn nípa ìlò lábẹ́ rẹ̀ ni a ti rí gbólóhùn àlàyé gbólóhùn ìkìlọ̀ àti gbólóhùn ìbéèrè pèsìjẹ Ní ọ̀nà kejì a tún wo ìtayọ àwọn ọ̀nàèdè inú ewì náà bí i òwe àkànlò èdè àfiwé tààràẹlẹ́lọ̀ọ́ Àwítúnwí ìfọ̀rọ̀gberọ̀ àṣọrégèé àsọdùn ìfohunpènìyàn ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ bí ọfọ̀ oríkì àti orin Nígbà tí a wo gbogbo ewì yìí lápapọ̀ tí a ṣe òǹkà àwọn gbólóhùn inú u rẹ̀ iye oríṣìí gbólóhùn nípa ìlò tí ari jẹ́ mẹ́ta Nígbà tí a ro gbogbo àwọn gbólóhùn wọ̀nyí pọ̀ tán wọ́njẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé mẹ́wàá Àbùdá tí a lò láti yan gbólóhùn wa ni òfin ìfààgègbà láti mọ gbólóhùn tí yio ta ìyòókù yọ Gbólóhùn àlàyé ni òǹkọ̀wé ṣàmúlò jùlọ lábẹ́ gbólóhùn nípa ìlò Èyí kò yẹ kó ya wa lẹ́nu nítorí a tí mọ̀ pé àlàyé ganan ni òǹkọ̀wé ń fi ewì Aṣọ ìgbà ṣe Gbólóhùn àlàyé yìí ni a máa ń fi sọ bí nǹkan bá ti rí Gbólóhùn kí gbólóhùn tí kò bá jẹ ti àṣẹ tàbí ìbéèrè gbọdọ̀ jẹ́ gbólóhùn àlàyé gẹ́gẹ́ bí ìlò wọn Nínú ewì Aṣọ ìgbà gbólóhùn àlàyé jẹyọ ni ìgbà ọ̀tàlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀tadínmẹ́jọ Àpẹẹrẹ ìjẹyọ irúfẹ́ gbólóhùn yìí ni a lè tọ́kasí báyìí nínú Pákáleke ìdúró ó sí ìbẹ̀rẹ̀ ó sí òunlọ̀rọ̀ ti i ba ẹní gbọdọ̀ mì ọmọ ni ọmọ ni ikú ọmọ ni payí talẹ̀ ọmọ o ọmọ o ikú mòńwọmọ ni pàgàn wàhálà tíí pẹran ọ̀jẹ wàhálà ọ̀hún níí bí olówó olówó nù oi ìlà Bákan náà nínú ewì Ògo ni Àbófo ni? A tún rí àpẹẹrẹ mìíràn Omi gbojú ara ilé omusẹ́ gbojú ara oko gbogbo ilẹ̀ ló wá rìrí ohun tó yẹ lóhun àmúṣògo ó wá dohun àmúpàyàn wọ́n mohun àmúṣògo onílẹ̀ wọ́n fi ń tágbègbè ibòmíìn ṣe wọ́n dájú ọmọ orílẹ̀ wọ́n ń bàná omi àpọnmu wọ́n ń boko wọn jẹ́ kọ́rọ̀ má dàìlèèfọhun oi ìlà A tún rí gbólóhùn ìkìlọ̀ nínú ewì Aṣọ ìgbà òǹkọ̀wé lò ó ni àlòyẹ irúfẹ́ gbólóhùn yìí ni a máa ń fi ń kílọ̀ fún ènìyàn òǹkọ̀wé lọ gbólóhùn yìí náà lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání nínú ewì rẹ̀ Ó jẹyọ ní ìgbà irinwó lé ní mẹ́ẹ̀ẹ́dógún Irúfẹ́ gbólóhùn ìkìlọ̀ ni a rí nínú ewì orí jẹ́ ń lọ́ tàá wọn a ní orí yámi yọ̀tá àdúgbò ewì fóníwá kó yé gbàdúrà tí ó pé ẹ kìlọ̀ fẹ́lẹ́yìn kò yé tọrọ nǹkan tí ó tọ̀nà oi ìlà A tún rí àpẹẹrẹ mìíràn nínú ewì ẹ̀yìnlàárò Ó ni ìwọ akẹ́kọ̀ọ́ tí ń kàwé tètè pàtàkì mọ́lẹ̀ kò ó ya ajítannámọ́rí má jẹ̀ẹ́ kọ́wọ̀ọ́ rẹ̀ gbọ̀n ó rè torí òní kọ́ torí ọ̀la ni akẹ́kọ̀ọ́ tó fàsìkò tafàlà irú wọn ni jẹ́ abẹ́sin káwọ́ lẹ́yìn ẹgbẹ́ wọn oi ìlà Bákan náà a tún rí gbólóhùn ìbéèrè pèsìjẹ náà Èyí ni gbólóhùn tí a máa ń fi ṣe ìbéèrè ohun kan tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò mọ̀ Irú gbólóhùn yìí kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ nínú ewì Aṣọ Ìgbà ìgbà mẹ́tàlélógójì náà ló jẹyọ Díẹ̀ lára irúfẹ́ gbólóhùn ìbéèrè pèsìjẹ ní yí nínú ewì Lẹ́tà sí Ẹwà mo bí ọ́ Ẹwà ṣe ayé tító o wa yìí ṣe é yangàn láwùjọ? ṣ ó o rántí Bẹ́wàjí Tó rẹwà tó sì ń hùwà bí i rẹ̀? oi ìlà Síwájú sí a tún rí àpẹẹrẹ mìíràn nínú ewì kínínla oṣù wo léyì? fẹ́búárì oṣù èrelè ń kọ oi ìlà Bójò ó rọ̀ Báwo ni ìtura ó ṣe wà oi ìlà ÀTẸ ÌTAYỌ GBÓLÓHÙN NÍPA ÌLÒ Gbólóhùn Iye ìgbà ìjẹyọ Àpapọ̀ iye ojúìwé Àlàyé Ìkìlọ̀ Ìbéèrè pèsìjẹ Ohun tí àtẹ òkè yìí ń sọ fún wa nipé gbólóhùn alálàyé ní ó gba ìtayọ nínú gbólóhùn nípa ìlò Nítorí tí ó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àlàyé ló máa ń pòjù nínú afọ̀ tí òǹkọ̀wé ṣàmúlò fún iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ Pàápàá jùlọ nínú ewì alákọsílẹ̀ Nígbà tí a gbé àwọn ọ̀nà èdè yẹ̀wò èyí tí o ní ìjẹyọ jùlọ ní àwítúnwí ó jẹyọ ní ìgbà ogóje lábẹ́ àwítúnwí yìí ni àti rí àwítúnwí ẹlẹ́yọọ̀rọ̀ àwítúnwí àkùdé gbólóhùn àti àwítúnwí èrò A ó wo irúfẹ́ àwọn àwítúnwí yìí lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan bí òǹkọ̀wé ṣe fihàn nínú ewì rẹ̀ Àpẹẹrẹ àwítúnwí àkùde gbólóhùn nínú Lẹ́tà sí Ẹwà ó tú ẹkún torí àwọ̀ ara rẹ̀ tó hunjọ ó bú ẹkún torí ẹwà tó ń wọ̀kun oi ìlà Àpẹẹrẹ mìíràn nínú sisí Akadá ó bọ́ lọ́wọ́ ọmọ ti ń jẹ́rú Ó bọ́ lọ́wọ́ sisí akadá oiìlà Bákan náà a tún rí irúfẹ́ àpẹẹrẹ Àwítúnwí ẹyọọ̀rọ̀ nínú inú níkà imú kò gbóòórùn abínú ẹní Imú rí kán ń bó lásán ni oi ìlà Òmíràn nínú Pákáleke isinmi ìsinmi isínmi ìsinmi wẹ̀ẹ̀ Ìsinmi kì í sì fẹ́dàá tín bẹ láyé Ìsinmi kì í sí fẹ̀nìyàn ti ń bẹ lóókè èèpẹ̀ oi ìlà Bákan náà ni a rí irúfẹ́ àwítúnwí èrò nínú ẹwà náà àpẹẹrẹ rẹ̀ ni a rí nínú Ẹ̀yìnlàárò Ọmọdé ilé tó ṣubú tó bojú wo wájú ó fẹ́ wàẹní tí yóò fòun sẹ̀fẹ̀ ni àgbà tó sì ṣubú tó wẹ̀yìn wò kò fẹ́ kí igbọ̀ǹgbò kan ó fòun lépo lẹ́ẹ̀mejì ni iná èsì kì í jóni lẹ́ẹ̀mejì ni wọ́n wí oi ìlà Àpẹẹrẹ mìíràn nínú Ṣáágo Ń Búgò pálágbádá ò mọ́lé tò pálágbádá ó mọ̀lu ṣe oi ìlà A rí i pé òǹkọ̀wé ṣe àmúlò Àwítúnwí Akùdé gbólóhùn ẹlẹ́yọ́ọ̀rọ̀ àti èrò láti jẹ́ kí àwọn kókó tí ó ni lọ́kàn wọni lákíra látàrí ìgbọ́kànró àti tọ́kasí kókó ohun tí ó ń sọ Ọnàèdè tó tún pọwọ́ lé Àwítúnwí ni òwe ó jẹyọ nígbà oókànlélàádọ́rùnún òǹkọ̀wé ṣe àmúlò òwe yìí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wa láti ìgbà tí àlàyé tí dáyé ó hun ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ó sí tún ṣe àtúnrọ fún àwọn òwe mìíràn nínú ewì Aṣọ Ìgbà Irúfẹ́ àtúnrọ òwe tí òǹkọ̀wé ṣàmúlò ni a rí nínú kókó kẹ́rinin Ẹ̀yìnláàró ṣé mọ̀kàn mọ̀kàn loyè i kàn obitun òń ń bọ̀ wà dìyá káà oiìlà Bákan náà nínú ewì Àgbà kú jàmbá ṣèlú Ni kókó kẹ́rin kan náà ó ní Bọ́mọdé ń gégi nígbó Àgbà ni mọlẹ̀ tí o sun oi ìlà Síwájú sí òǹkọ̀wé tún ṣàmúlò òwe alákànpọ̀ nínú ewì rẹ̀ igi kan ó dá gbó ṣe ní kókó ọ̀rọ̀ kìíní ó ní Tẹ́tí o gbọ́ àwé Èèyàn ló ń bẹ lẹ́yìn orò loorò fi ń ke bí ò séèsún òun ìtàkùn igbó ò bá tí sí torí igi kan ò lè dágbó ṣe bí ò sóhun ti ń lù lálẹ̀ odò ìre mi kò lè ṣàdédé jo lórí omi gaga ọwọ́ kan o jẹ pera rẹ̀ ló ṣù ẹ̀dá kan ò sì jẹ́ pera rẹ̀ láwa oi ìlà Òǹkọ̀wé sí tún ṣàmúlò òwe gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ganan A rí èyí lọ́pọ̀ yantunru irúfẹ́ rẹ̀ ní ewì Àgbà kù jàmbá ṣèlú nínú kókó ọ̀rọ̀ kẹ́rinun ó ní Wọ́ lágbà ò sí ìlú ṣe bẹ́ẹ̀ ó bàjẹ́ Baálẹ̀ ilé kú ilé ṣe bẹ́ẹ̀ o dahoro oi ìlà A tún rí àpẹẹrẹ mìíràn nínú ewì ásù fọnmú nínú kókó ọ̀rọ̀ kẹfà ó ní pé mọ̀sà mọ̀jà làá mọakin Akin tó mọ̀jà tí ò mọ mọsà irú wọn ni biákin ibòómìn lọ oi ìlà Ọnà èdè tó tayọ mìíràn ní ìfọ̀rọ̀gbèrọ̀ ó jẹyọ ní ìgbà àádọ́rinléméjì ìfọ̀rọ̀gbèrọ̀ yìí ni Ọlábọ̀dé pè ni Àjùmọ̀rìn ọ̀rọ̀ Èyí tí o jẹ́ ọ̀nà èdè to máa ń bá ìbádọ́gba gbólóhùn rin Irúfẹ́ ọnà èdè yìí larí fàyọ nínú ewì kábíyèsí lábẹ́ kókó ọ̀rọ̀ karùnún ipò ọba dohun àmúṣere ipò Aláyélúwà ti dohun ẹ̀fẹ̀ àyè ọba aládé ti dohun yẹpẹrẹ oiìlà A tún rí àpẹẹrẹ mìíràn lábẹ́ kókó ọ̀rọ̀ kẹ́ta nínú sisí Akadá Bó o tí ń jijo súfèéntàka bẹ́ẹ̀ lò ń jíjó wàmọ́ọntìpẹ̀ oi ìlà Ọnàèdè tó tún tayọ ni àkànlòèdè ó jẹyọ niigba àádọrindínmẹ́rin nínú ewì Aṣọ Ìgbà Àkànlò èdè ni lílo èdè lọ́nà tí ó yàtọ̀ sí bí a ti ṣe le lòó nínú èdè ojoojúmọ́ Ìtumọ̀ tí à ń bá nínú rẹ̀ yàtọ̀ sí ohun tí a bá nínú ìhun òkè Èyí tí Yorùbá ń lò nigbàtí wọ́n kò bá fẹ́ sojú abẹ níkòó Òǹkọ̀wé ṣe àmúlò rẹ̀ ganan irúfẹ́ rẹ̀ ni ó hàn nínú ewì irú kìírú Ọlọ́pàá ó ní Báwakọ̀ bá tí palẹ̀ láró Àbùṣe ti bùṣe oi ìlà Àpẹẹrẹ mìíràn nínú ewì ÀbOlódùmarè ń tòògbé? Lábẹ́ kókó àkọ́kọ́ ó ní Gbogbo ayé ń pé wòlí lẹ́ni Ọlọ́run kò pẹ́ kò jìnnà tákàrà tú sépo oi ìlà Òmíràn nínú ewì oníkàn yìí rọra lábẹ́ kókó kejì Ọ̀fọ́nọ̀n tí tọ̀ ọ́ gbẹ̀gìrì kẹ́lẹ́kọ kẹ́kọ ẹ̀ lọ́wọ́ àti àṣẹ aíbùkí fẹ̀jẹ̀ sínú tutọ́ funfun jáde ni oi ìlà Ọnàèdè mìíràn tó tún jẹyọ ni àfiwé ti ìrìnoye àti Ọláyọdé pé ní ọ̀nà ti a ṣe nípa síṣọ nǹkan mìíràn kí a wá máa fi ojú nǹkan mìíràn wo ohun tí a ní lọ́kàn ganan tí a sí máa ń ṣàmúlò rẹ̀ lójoojúmọ́ àti nígbà gbogbo Àfiwé yìí jẹyọ ni ìgbà àádọ́talémẹ́ta nínú rẹ̀ ni àti rí àfiwé tààrà àti àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ Àpẹẹrẹ àfiwé tààrà bí o ṣe jẹyọ nínú ewì Ẹ̀yìnlàárò lábẹ́ kókó kẹ́rin Tó o dẹni àpésìn bí òkè Bàdàn oi ìlà Nínú Gbeborun Lábẹ́ kókó kẹ́ta ó ní Lẹsẹ̀ kù bí i fọ́nrán ọwọ́ oi ìlà àti lógunlékòó kò ridìí jókòó bí i ìgbà oiìlà Àpẹẹrẹ mìíràn nínú ewì ṣáágo ń búgò lábẹ́ kókó kejì Gbogbo mọ̀lẹ́bí alágbàá ni wàyà mú bí gaàri oiìlà Bákan náà a tún rí àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ èyí tí a ń fi pé ohun tàbí ẹní kan ni ohun tí a fẹ́ fi wé ganan tó ní àbùdá ìrísí tàbí ìhùwàsí tí a ni lọ́kàn Àpẹẹrẹ èyí ni òǹkọ̀wé fihàn nínú ewì sisí Akadá lábẹ́ kókó kẹ́ta Ó bọ́ lọ́wọ́ ọmọ tí ń jeérú oiìlà Àti nínú ewì Ẹ̀yìnláàró ó ní Ènìyàn kò gbọdọ̀ ṣẹ̀ṣe òkété oiìlà Àpẹẹrẹ mìíràn tí a tún rí ni o wà nínú ewì Àgbàkú jàmbá ṣèlú ó ní Ààtàn làgbà kò ṣẹ́ gbin tí kò gbà oi ìlà Ọnàèdè mìíràn tó tún gba ìtayọ ni àṣọrégèé àsọdùn èyí ni ọnà èdè tó jẹyọ níbi tí a bá ti ṣe àbùmọ́ nǹkan ju bí ó ti tó ganan lọ èyí ni mímọ́ nǹkan ni àmọga ohun ni àwọn onímọ̀ mìíràn pé ni àpọ́npo Àṣọrégèé yìí jẹyọ nígbà oókàndínlógún Àpẹẹrẹ bí òǹkọ̀wé ṣe ṣe àfihàn rẹ̀ nínú ewì Aṣọ Ìgbà Lábẹ́ kókó kẹfà nínú gbéborùn ó ní Ẹjọ́ ẹlẹ́lọ́ làwé rò lètè kù fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ oi ìlà àti Ó kùlùbọ́ ètè kíri agboolé oi ìlà A tún rí àpẹẹrẹ mìíràn nínú ewì oṣù ìsọnu Oṣù tí mùjúmùwà ń forí pená ìgi láàrò oi ìlà Bákan náà ewì sisí akadá ó ní Ó tún lè wọ amákọ tọ̀ọ́Sòkòtò oi ìlà àti nínú irun jímọ̀ ńilọrin ó ní wọn tí ń fodó ìbúlẹ̀ jẹun oi ìlà Ọnàèdè mìíràn tó tún gba ìtayọ ni ìfohunpènìyàn èyí ni kí a máa gbé ìṣeṣí ènìyàn wọ ohun ẹlẹ́mìí mìíràn tàbí ohun tí kò tilẹ̀ lẹ́mìí rárá A rí èyí nínú ewì tí òǹkọ̀wé pé ni Àbùkù kan ẹ̀wà Ọmọ aráyé kọ̀ wọn ó wẹ́wà wá mọ́ Erèé dẹni àbùkù láwùjọ oúnjẹ Gbogbo ọmọ aráyé kẹ́yìn sẹ́wà oi ìlà Àpẹẹrẹ mìíràn ni Lẹ́tà sí Ẹwà lábẹ́ kókó kẹ́ta Ẹwà mi ọ̀wọ́n Àánú rẹ ṣe mi jọjọ O gbẹ́rù kan àrà tó lóòrìn rù Ẹrú ìbànújẹ́ ayé lẹrù ọ̀un tímo mí ketekete oi ìlà Gbogbo ìfohunpènìyàn tí a rí ṣáájọ nínú ewì yìí jẹ́ mọ́kànlá ii Ọnàèdè mìíràn tí a kò lè fojú fò ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Yorùbá Èyí tí ó lè jẹyọ bí oríkì tàbí ọfọ̀ Èyí jẹyọ nígbà márùnún Irúfẹ́ ibi tí ọfọ̀ tí jẹyọ Nínú ewì Pákáleke Páká páká Kì í tan ní lé páká leke pọnlàpọnlá Kì í kúrò lọ́rọ̀ bàtá nígbà kọ̀ọ̀kan ìgbì omí lè bi eweé wájú kí gbì tún sẹe sàbẹ̀wẹ̀ sẹ́yìn ìṣe ewé ojú omi oi ìlà Àpẹẹrẹ ewì tí o ṣàfihàn oríkì ni ewì Ọpẹ́ PÉdùmarè Dákú Kábíyèsí rẹ Èdùmarè Ọba ńlá tó jọba ayé lọ Alágbára lórí ohun gbogbo Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé Ẹlẹ́dàá adẹ́dàá oi ìlà Ọnàèdè mìíràn tí a tún rì fàyọ ni orin èyí sí jẹ́ orin ìréwèdeorin erémọdé Òǹkọ̀wé ṣe àmúlò èyí ni ìgbà mẹ́rinin nínú ewì Aṣọ Ìgbà ó fí orin yìí pé àkíyèsí wa sí bí àwọn ọmọdé tí máa ń ṣe nínú eré tó ni orin náà Èyí ni ó jẹ́ kí òǹkọ̀wé lọ orin tó dá lórí kókó ọ̀rọ̀ tó bá ìgbà yìí irúfẹ́ orin náà ni a rí nínú ewì Àbùkú kan ẹwà Oríṣìíríṣìí ẹwà ló wà Lówódé pàńtirẹgẹ dúrọ́ọ̀mù sókótó káúrá pàńtirẹgẹ dúrọ́ọ̀mù io ìlà A tún rí òmíràn nínú ewì òǹkọ̀wé yìí rọra Oníkàn yìí rọra Terejìngín Oníkàn yìí rọra Terejìngín Ìwọ́ ká Èmí ká Terejìngín Tèmi ṣe leèdìjà Terejìngín Oníkàn yìí rọra Terejìngín Bó dìjà kó dìta Èmí ó ní í sá Terejìngín oi ìlà Bákan náà nínú ewì BásaBása Mà ta sómi wẹ́rẹ́wẹ́ré Mà ta sómi wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ Só ma tá A wóyá woyà woya A básá basà bańsa Ewú rẹ̀ ilé rẹ̀ Sálámọ́tù Àgùntàn ilé rẹ Sálámọ́tù Àdùkẹ́ Làwa ń ba ṣere Olówóẹyọ Àdùkẹ́ Làwa ń bá tayọ Olówó ẹyọ oi ìlà Akéwì ń pàrọwà fún àwùjọ láti máa rọra ṣe àti pé ohun tó bá tó sí lágbájá ó yẹ kí ó lọ sí làkásègbè pẹ̀lú Òhun ni òǹkọ̀wé fi orin yìí sọ fún àwùjọ nínú Oníkàn yìí Rọra Bákan náà nínú BásaBása a rí pé ọ̀nà ìdárayá àti fún pípe ìrònú wa sí ohun tí o fẹ́ sọ nínú ewì náà Ṣùgbọ́n tí a bá wò ó dáradára a ó rí pé orin yìí kò ní ìtumọ̀ kan san án nítorí ó dàbí irú èyí tí a máa ń ba pàdé nínú orin ọ̀nà ẹnu Àpẹẹrẹ irú orin báyìí ni Alálọmọ́tandainin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ÀTẸ ÌTAYỌ ỌNÀ ÈDÈ ỌNÀ ÈDÈ ÌGBÀ ÌJẸYỌ ÀPAPỌ̀ ÌJẸYỌ Àwítúnwí Elẹyọ ọrọ Àkùdé gbólóhùn Èrò Òwe Ìkìlọ̀ Àlàyé Ajẹmọ́tàn Ìfọ̀rọ̀gbèrọ̀ Àkànlò èdè Àfiwé Tààrà Ẹlẹ́lọ̀ọ́ Àṣọrégèé àsọdùn Ìfohunpènìyàn Ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Ọfọ̀ Oríkì Orin Gẹ́gẹ́ bí àtẹ òkè yìí ṣe fihàn a ó rí pé àwítúnwí ẹlẹ́yọọ̀rọ̀ ni ó gba ìtayọ lábẹ́ awutunwi ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé òǹkọ̀wé fẹ́ kí òǹkàwé di àwọn kókó ọ̀rọ̀ tí o tẹnumọ́ mú kí ó le wà ni ọ̀kan wọn Nítorí Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọ̀rọ̀ tí ènìyàn bá ń tẹnuwọ́ ṣá ṣa bí kòbá dun á jẹ́ pé ó dùn mọ́ ni ohun tó bá sí dun ni ni pòjù lọ́rọ̀ ẹni ìdí nìyìí ti òǹkọ̀wé fi lo àwítúnwí yìí kí a ba lé rí òkodoro ọ̀rọ̀ inú ewì náà Bákan náà tí a ba wo òwe tí òǹkọ̀wé ṣàmúlò a ó rí pé òwe ìkìlọ̀ ní ó gba ìtayọ lábẹ́ ìsọ̀rí yìí Ìdí nì pé òǹkọ̀wé ṣàmúlò rẹ̀ láti dẹ́kun àwọn ìwà tí kò dára ni àwùjọ wa tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ lọ́wọ́ Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa sọ pé àbọ̀rọ̀ là ń sọ fọ́mọlúàbí bí ó bá dẹ́nú rẹ̀ á di odìdi Bákan náà lábẹ́ ìtayọ àfiwé a rí pé àfiwé tààrà ni ó gba ìtayọ nítorí pé ohun ni o ni ìtayọ tí ó ju ẹlẹ́lọ̀ọ́ lọ Òǹkọ̀wé ṣì jẹ́ kí ó rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ kí kókó ọ̀rọ̀ ti òhun ń sọ ó yẹ́ ènìyàn yékéyéké kí òkodọro ọ̀rọ̀ lè hàn sí ènìyàn Síwájú sí i nígbà tí a ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà èdè wọ̀nyí lápapọ̀ èyí tí ó gba ìtayọ jùlọ ni àwítúnwí pàápàá jùlọ àwítúnwí ẹlẹ́yọọ̀rọ̀ tí o ní ìjẹyọ ọgọ́rin Ìdí tí ó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé òǹkọ̀wé lòó láti ṣe ìtẹnumọ́ fún àwọn kókóọ̀rọ̀ inú ewì Aṣọ Ìgbà láti jẹ́ kí àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ rinlẹ̀ lọ́kàn òǹkàwé Kí ó ba le ni ìgbọ́kànrò àti pé kí ohun tí òǹkọ̀wé ń sọ lè dùn látàrí àti wọni lára ORÍ KẸ́RININ ÌṢEWẸ́KÚ ÀWỌN ÈRÒJÀ INÚ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ ÌFÁÀRÀ Nǹkan ti afẹ́ wò lábẹ́ ìṣewẹ́kú àwọn èròjà inú ewì Aṣọ Ìgbà ni ìbáramu tàbí ìbádọ́gba pẹ̀lú gbogbo àwọn èròjà inú ewì yìí Èyí ni pé a fẹ́ mọ̀ bóyá gbogbo àwọn èròjà tí òǹkọ̀wé kójọ sínú iṣẹ́ rẹ̀ bá ara wọ́n ṣiṣẹ́ dọ́gba Ìṣe rẹ́gí bí ìdodo ẹ̀fọn yìí ló jẹ wá lógún nínú òdiwọ̀n yìí Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ sáájú pé ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo ni gbogbo àwọn èròjà inú afọ̀ kan gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ èyí lọ́ fàá tí àjọṣepọ̀ tó dán mọ́rán fi wà láàrín àwọn òdiwọ̀n tí onímọ̀ ìṣọwọ́loèdè ma ń ló kí iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ náà lè mú àbájáde tó yanrantí wà Ọ̀rọ̀ àwọn òdiwọ̀n náà wá dàbí bí òǹgbìn kò gbìn kí ni òǹka yóò ka? Bí òǹka kò ka kíni òǹra yóò rà Bí òǹra kò rà? Kí ni oúnjẹ yóò jẹ? Àwọn òdiwọ̀n wọ̀nyí máa ń jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ ni Ìgbà tí a rí èròjà ajẹmáfọ̀ kó jọ pọ̀ ni a mọ̀ pé ó yẹ kí á sọ wọ́n pọ̀ kó le ní ìtumọ̀ Ìgbà tí a bá sọ wọ́n pọ̀ tán ni a máa fẹ́ wo bí wọ́n ṣe ta ara wọn yọ sí àti bí wọ́n ṣeṣe wẹ́kú sí èyí tí a fẹ́ ṣe níbi yìí Oríṣìíríṣìí ni àwọn òfin tí a le lò láti wo bóyá àwọn èròjà inú afọ̀ kan ṣewẹ̀kú tàbí wọn kò ṣewẹ́kú Lára irú àwọn òfin náà ni ìruké ìfa òténté yọ ìtẹ̀léìtẹ̀lé ni ìlà ìpìlẹ̀ ìsọdipẹ̀tẹ́lẹ̀ ìhà ìkọsíra olóòró àti ìhà ìkọsíra oníbùú Ìruké ni ki ìhun kan máa ń ruké sókè ju ìhun tó kùn lọ Èyí tí a ó fi mọ̀ bóyá bí ó ṣe yẹ kí èdè akópa ìṣẹ̀lẹ̀ wà ni ó ṣe wà Ìfa òténtéyọ ni a ti máa wò ó bóyá èròjà tó ní ìruké tó ga jùlọ náà ni ìmọ̀lára rẹ̀ pòjù àwọn tó kùn lọ Òmíràn ni ìtẹ̀léìtẹ̀lé ní ìlà ìpìlẹ̀ òhun ni yóò jẹ́ kí a mọ̀ bóyá ààtò àwọn èròjà inú iṣẹ́ aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ wà bó ṣe yẹ tàbí ó mẹ́hẹ Ní abala yìí ni a ó ti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn èròjà yìí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí inú ewì Aṣọ Ìgbà ÌṢEWẸ́KÚ AJẸMỌ́ KÓKÓ Èrò tó gún òǹkọ̀wé ní kẹ́ṣẹ́ inú láti gbé ewì rẹ̀ jáde ni a mọ sí kókó inú afọ̀ kan Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà kókó máa ń fara pé ìṣẹ̀lẹ̀ inú afọ̀ ṣùgbọ́n ó yàtọ̀ ṣíra Iṣẹ́ tí òǹkọ̀wé tàbí akéwì fẹ́ràn sí àwùjọ ganan ni kókó inú afọ̀ Tí a bá wo inú àtẹ ìtayọ àwọn kókó inú ewì Aṣọ Ìgbà a ó rí i pé ìṣewẹ́kú wà nínú kókó tó gba òtéńté tàbí tó tayọ àwọn tó kùn yọ torí ó wà ni ìbámu pẹ̀lú èrò ọ̀kan òǹkọ̀wé nípa onírúurú èrò ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó lọ ní àwùjọ tó fẹ́ fi hàn àwa òǹkàwé Nínú ìwé ewì Aṣọ Ìgbà kókó pàtàkì méje ni a rí àwọn ni ìṣèlú ìkìlọ̀ ìwà ìgbésí ayé ẹ̀dá ìwà obìnrin iṣẹ́ ọba ìfẹ̀tọ́dunni àti ọ̀rọ̀ ìyànjú Nínú kókó méjèèje èyí tó dá lórí ìgbésí ayé èdè ló gba òtéńté tí ó sí ta àwọn kókó tó kun yọ Kókó ọmọ abẹ́ mẹ́fà ní ó ní nínú èyí tí a tì rí oríṣìíríṣìí ìṣẹ̀lẹ̀ tó dá lórí ìgbésí ayé ẹ̀dá lábẹ́ rẹ̀ ni a ti rí ewì pákáleke kin la oṣù wo léyì? ipò ọlá tẹ̀mi ó ṣòro àbOlódùmarè ń tòogbé? Àti igi kan ò dá? Gbóṣe Gbogbo ìhùwàsí àti ìṣeṣí àwọn ènìyàn pàápàá àwọn olórí ilẹ̀ wa ni ó gún Òǹkọ̀wé ní kẹ́ṣẹ́ inú láti kọ ewì Aṣọ Ìgbà iṣẹ́ àwọn adarí ọmọ iléìwé gíga pẹ̀lú ìgbé ayé àwọn ènìyàn lápapọ̀ ni àsìkò tí a wà yìí ni òǹkọ̀wé fẹ́ nà hàn àwa òǹkàwé Bí àpẹẹrẹ nínú ewì pákáleke òǹkọ̀wé fi ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé gbogbo ẹ̀dá láyé yálà obìnrin ọkùnrin ọmọdé tàbí àgbàlagbà ọ̀gá ni tàbí ọmọṣẹ́ kò sí ẹni tí ó ni ìbàlẹ̀ ọ̀kan ni gbígbé wọn ní ilé ayé Yálà lọ́sànán tàbí láṣalẹ́ láṣalẹ́ tàbí lówurọ̀ Ó ní Àájẹ áá mu Kì í pọkàn ẹni pọ̀ lójú ọ̀sán Bó bá tún dọjọ́ alẹ́ Inú fuu àyà fún ni gbalẹ̀ ìpáyà a sì gbọkàn nítorí ẹlẹ́gírí Lóòtọ́ọ́ ara lè sùn Àmọ́kàn ó sinmi Ẹní bàlágà tó táyaá ni A máa káyà sókè kó Má sọjà rà A máa bẹ̀rù kó ma ṣe gbeégun eléegun Ẹ̀lẹ̀ tí ń fẹlẹṣe héélà a bẹ̀rẹ̀ sí ṣojo Òjòjò ojo ká má sílẹ̀ yà ni Tani kò mọ̀ pójà òkùnkùn lọ̀rọ̀ lọ́kọláya oi ìlà Ewì yìí fihàn pé ìṣewẹ́kú wà lórí kókó tí ó gbé òǹkọ̀wé nínú láti kọ ewì yìí nítorí ó bá èrò ìjìnlẹ̀ Yorùbá mú pé ilé nìyí òun aya ò ilé nìyí òun ọmọ èèyàn èé ṣe fújà láì nílé Èyí ní ó jẹ́ kí èrò òǹkọ̀wé ṣe rẹ́gí bí ìdodo ẹ̀fọn ÌṢEWẸ́KÚ AJẸMỌ́ ÌṢẸ̀LẸ̀ Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì márùnún ní a rí nínú ewì Aṣọ Ìgbà Nínú àkíyèsí wa ìṣewẹ́kú tó jíire wà láàrín àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí òǹkọ̀wé fi ewì gbé kalẹ̀ sínú ìwé rẹ̀ àwọn àkọlé ewì yìí pẹ̀lú èdè tí òǹkọ̀wé ṣàmúlò láti fi gbé wọ́n kalẹ̀ dá múṣémúṣé Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ewì tí òǹkọ̀wé pé àkọlé rẹ̀ ni oníkàn yìí rọra a rí pé ìṣẹ̀lẹ̀ láàárín àwa ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà àti àwọn aláwọ̀ funfun tí wọn fẹ́ gba ohun ìní wa mọ́ wa lọ́wọ́ Kò sí ẹní tí ó máa gbọ́ tàbí ka ewì yìí tí kò ní mọ̀ pé àwọn ènìyàn àwùjọ pàápàá olórí ilẹ̀ wa ni òǹkọ̀wé bu ẹnu àtẹ́ tù tí ó jẹ́ pé wọ́n ò fẹ́ mọ̀ bóyá ẹnìkan jẹun tàbí kò jẹun bámúbámú ni wọ́n yó tí wọn ò sì bojú wẹ̀yìn Ẹ wò ó bí òǹkọ̀wé ṣe gbé kalẹ̀ Ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ Ṣebí kóńkó jabele ni Kálukú ló ń ṣe tirẹ̀ lọ́tọ̀tọ̀ Àtòhún rìn wá ló fi jàgùdà Páálí bọ́rọ̀ Páì kọ́wọ̀ọ́rìn ejò Ní kó ìyá jomejò Péji kan kì í jẹ́ gbó Àpapọ̀ ìtàkùn nì jẹ́ ìtí Láì wọ̀tàn ìṣẹ̀dálẹ̀ kóówá wọn Ọmọ afọ̀kun ṣọ̀nà so wọ́n pọ̀ Ó sọ wọn dodindi tán Ọmọ afọ̀kunṣọ̀nà bá sọra rẹ̀ di kọ̀ǹkọ̀ Tí í ṣe baálẹ̀ odò Wòsọ̀dèmí fẹ́ doníṣẹ̀ Ajinilọ́kọ fẹ́ daya ẹni mùsùnmusùn ire ọkọ tó sọ Jìngbìnnì mọjú àtọ̀húnrìnwá Àtọhúnrìn fẹ gbalẹ̀ lọ́wọ́ onílẹ̀ oi ìlà Àrokò tí òǹkọ̀wé ń pa fún àwùjọ nì pé àfọwọ́ ṣowọ́pọ̀ o ṣe kókó o ṣe pàtàkì nítorí aì nì ìfọwọ́ṣowọ́pọ̀ àwọn ẹ̀yà Ìgbò Haúsá àti Yorùbá ni o jẹ́ kí àwọn Òyìnbó aláwọ̀ funfun jẹ gàbalé adúláwọ̀ tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ohun tí a bá ń ṣe ni kì í dára lójú wọ́n Nítorí ìdí èyí ní wọ́n fi máa ń pèdè pé ọpọlọ orí àwọn adúláwọ̀ lápapọ̀ dúdú bìribirì nítorí náà àwọn ò lórò pé ohun dídára kan lè ti ilẹ̀ adúláwọ̀ jáde Títí kan ọkọ òwò wa ni ó jẹ́ pé àwọn ní wọ́n sọ iye àti bí a ṣe máa gbé gbogbo rẹ̀ jáde tí yóò fi di odindi Nítorí òǹkọ̀wé gba gbogbo wa ńimọ̀ràn láti ṣe ara wa ni òṣuṣu ọwọ̀ tí o jẹ pé gaga ọwọ̀ kan ò le ṣe ohunkóhun Kí àwọn Òyìnbó amúnisìn lé ṣe bí ọba lórí wa kí wọ́n yẹ pé wá ní ọ̀bọ ìmàdò àti pé kí wọ́n le jẹ́wọ́ lórí ohun inú ilẹ̀ wa Bákan náà tí a bá tún wo ìṣẹ̀lẹ̀ kejì tí òǹkọ̀wé fi ewì gbé kalẹ̀ tí ó pè ní lẹ́tà sí ẹwà A ó rí i pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ láwùjọ wa ni òǹkọ̀wé gbé jáde nínú ewì yìí pàápàá jùlọ àwọn ọmọge tí ó bá jẹ́ pé wọ́n lẹ́wà díẹ̀ báyìí wọ́n yóò wá sọra wọn di anímáṣahun tí ṣe fún arúgbó bẹ́ẹ̀ ni yóò máa fún ọ̀dọ́ nígbà tí wọ́n ti sọra wọn di fàwọ̀rajà Òǹkọ̀wé ṣe àfihàn rẹ̀ báyìí Bẹ́wàjí tún ń nájà pèl àwọn baálẹ̀ ilé mẹ́rin láì jẹ́kìnínni kejì mọra wọn Tí wọ́n ti wínra nínú òwò ṣìná Wọ́n fẹ́ràn Bẹ́wàjí Bẹ́wàjí náà kò ṣàì fẹ́ wọn dé góńgó Tọ sán tòru àrìyá ni Ṣẹ̀ṣẹ̀ nínú Bẹ́wàjí í dùn Bó bá tí dágbo àwọn ọ̀rẹ́ Kùnrin tó ń fẹ́ Bẹ́wàjí kú àìmọkan mọ̀kàn Kò mọ̀ pé ìfẹ́ a faádìe ó dénú Ibi ká pa aájẹ loómọ Kò mọ̀ pé ìfẹ́ àìdọ́kàn ló ń bẹ lọ́kàn kọ́ọ́wá oi Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tí òǹkọ̀wé sọ nípa Bẹ́wàjí ni o ṣe wẹ́kú pẹ̀lú àsìkò tí a wà yìí nítorí ó di ọjọ alẹ́ kì í ọ̀pọ̀ obìnrin bí Bẹ́wàjí tó mọ̀ pé ẹwà ara kì í ṣe ìwà ìwà ló ṣe kókó Èyí náà tún bá ìgbà tí a wà yìí mú ni gbogbo ọ̀nà ÌṢEWẸ́KÚ AJẸMỌ́ AKÓPA Àwọn akópa ni ènìyàn tàbí ohun àfipènìyàn tí wọ́n kó ipa kan tàbí òmíràn láti mú kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú afọ̀ kan wá sí ìṣe Àwọn ni alátọ̀nà fún gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú afọ̀ kan Ohun tí a fẹ́ wò níbi ni bóyá ipò àti ojúṣe akópa inú ewì Aṣọ Ìgbà bá ìṣẹ̀lẹ̀ àti kókó ohun èdè ti wọ́n ń pé jáde mú A fẹ́ wo bí gbogbo àwọn èròjà wọ̀nyí ṣe ṣe régi pẹ̀lú ẹ̀dá ìtàn tàbí akópa tí ṣe àmúlò wọn Gbogbo ẹ̀dá ìtàn akópa tí a rí nínú ewì Aṣọ Ìgbà ni wọ́n ṣe wẹ́kú pẹ̀lú pò àti ojúṣe tí òǹkọ̀wé fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ọ̀tá ni ó jẹ́ akópa tí ó tayọ nínú ewì Aṣọ Ìgbà tí òǹkọ̀wé sì fún ni ojúṣe bí ẹní tí yóò jẹ́ kí àwọn ẹníyan múra gìdi sí ohunkóhun tí wọ́n bá ṣe nítorí bí ènìyàn ò bá lọ́tàá yóò kàn máa sèèyàn lọ́kàn ni kò sí ni múra nígbà kankan nítorí gbogbo rẹ̀ ni lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ Ìdí ni yí tí òǹkọ̀wé fi lo ewì yìí láti fi sí àwùjọ níyè nípa ohun tí a nílò ní ilé ayé Ó ní Bóní wá máa wí Wọn a ní Orí yà mi yọ́tá ilé Bẹ́lẹ̀yìn máa sọ̀rọ̀ Wọn a ní Orí yà mí yọ̀ta àdúgbò Ẹwí fóníwá Kó yé gbàdúrà tí ò pé Ẹ kìlọ̀ fẹ́lẹ́yìn Kó yé tọrọ nǹkan tí ò tọ̀nà Ẹ̀dá tí ń bẹ láyé Tí rú wọn ò lọtàá Irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ ò ṣere ni oi Gbogbo ohun tí òǹkọ̀wé sọ nípa akópa ọ̀tá ní o ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ewì yìí àti èrò òǹkọ̀wé láti fi ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ hàn sí gbogbo mùtúmùwà èrò yìí ganan bá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ èrò Yorùbá pé ilé ayé ilé ògún ni ogun layé ayé lòkun ènìyàn lọ̀ṣà Èyí ni pé ilé ayé kún fonírúurú ogun àti oríṣìíríṣìí làásìgbò Bákan náà tí a bá tún wo akópa mìíràn tí ń ṣe obìnrin nínú ewì orogún gbogbo ohun tí òǹkọ̀wé fi ṣẹ́nu ifá láti sé àpèjúwe obìnrin lórí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ Nítorí nínú ewì yìí ni a ti rí gbogbo ìwà àìtọ́ àìda tí àwọn obìnrin máa hùn síra wọ́n tí wọ́n bá jẹ́ orogún lọ́dọ̀ ọkọ kan náà Ó ní Ọ̀kan ṣoṣo póró lobìnrin dún Mọ lọ́wọ́ ọkọ Bí wọn bá de méjì Wọn a dòjòwú Bí wọn bá di mẹ́ta Wọn a dẹ̀ta ń túlé Bí wọn bá di mẹ́rin Wọn di ìwọ ló rìn mi ni Mọ rín ọ Tìyálé ti ìjàwó ò jẹ́ kọrin rẹ̀ kira Ńṣe ni wọn sóra wọn lọ́wọ́ Ti wọn sọ́ra wọn lẹ́sẹ̀ Wọn a má dọdẹ ara wọn oi ÌṢEWẸ́KÚ AJẸMỌ́ WÚNRẸ̀N ÈDÈ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ síwájú èdè jẹ́ nǹkan tí a kò le fojúfò nínú ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ ọ̀nà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ kan pàápàá tí ó bá jẹ́ wí pé tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè ni a lò Èdè jẹ òṣùnwọ̀n kan tí a ó fi mọ̀ bóyá èdè kan ṣe wẹ́kú tàbí kò ṣe wẹ́kú Lábẹ́ ìṣewẹ́kú ajẹmọ́ wúnrẹ̀n èdè yìí nǹkan tí a fẹ́ wò ni bóyá gbogbo àwọn wúnrẹ̀n èdè tí òǹkọ̀wé kójọ sínú iṣẹ́ rẹ̀ ló ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ tó fi ewì rẹ̀ rán sí àwùjọ A tún máa wòó bóyá ibi tó yẹ kí èdè kan ti wáyé ló tí wáyé tàbí pé ṣe ni òǹkọ̀wé kan lo èdè bó ṣe hùnún Bákan náà a tún máa wo bóyá wúnrẹ̀n èdè tó yẹ kó gba òtéńté lọ́lọ́wọ́jọwọ́ náà ló gbà á Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ló máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wa láti mọ bóyá ìṣewẹ́kú wà nínú àwọn wúnrẹ̀n èdè tí Dúró Adélékè kójọ sínú ewì rẹ̀ lẹ́yìn tí a tí lọ àwọn òfin ìṣewẹ́kú bí ṣíṣẹ̀ntẹ̀lẹ́ ìruké àti ìfa òtéńté yọ A rí i pé gbogbo wúnrẹ̀n èdè tí òǹkọ̀wé lò nínú ewì rẹ̀ ló ṣe wẹ́kú pẹ̀lú iṣẹ́ tó rán ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn Ìpele méjì ni a pín àwọn èdè tí o wà nínú ìwé ewì Aṣọ Ìgbà sí kí á ba lérí ààyè ṣe ìgbéléwọ̀n wọn Àwọn tí a fi ṣe ìgbéléwọ̀n ni gbólóhùn nípa ìlò Lábẹ́ rẹ̀ ni a tí rí gbólóhùn àlàyé ìkìlọ̀ àti gbólóhùn ìbéèrè pèsìjẹ Ìpele kejì ni àwọn ọ̀nà èdè tí a bá pàdé nínú ewì náà bí òwe àfiwé àwítúnwí àṣọrégèé àsọdùn ìfohunpènìyàn àti ọ̀rọ̀ ẹnu Yorùbá Lábẹ́ ìpín àkọ́kọ́ tó dá lórí gbólóhùn nípa ìlò gbólóhùn àlàyé ló gba òtéńté èyí nì pé ohun ló ni ìruké ju àwọn gbólóhùn tí wọ́n jọ wà ní ọwọ́ kan náà Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà gbólóhùn àlàyé ló máa ń wáyé jùlọ nínú afọ̀ lójú ayé eléyìí náà ni a bá pàdé nínú ewì Aṣọ Ìgbà Àti pé a ṣe mọ pé nínú ewì òǹkọ̀wé kì í kọ ọ̀rọ̀ kún ojú ìwé sokí lọbẹ̀ oge ni ó máa fi ṣe èyí tún jẹ́ ìdí mìíràn Yàtọ̀ ṣí èyí bí ó ṣe jẹ́ pé gbólóhùn ìbéèrè ló máa ń ṣáájú kí gbólóhùn àlàyé máa tẹ̀lé níbi tí wọ́n bà ti jọ jẹyọ èyí kò yàtọ̀ nínú ewì Aṣọ Ìgbà Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ Mo bí ó ẹwà Ṣe ayé tó o wa yìí ṣe é Yangàn láwùjọ? Lára àwọn ọdájú kùnrin bàyàkokoìnàkí To kọnu ìfẹ́ sí ọ Dípò k' ó o yankọ gíríkì Mímú lọ ń m'ọkùnrin láàmújùúlẹ̀ Ṣó o rántí Bẹ́wàjí Tó rẹwà tó sì ń hùwà bíì rẹ? Níbo l'owà lónìí? Ó ti yọ́ tán poopoo Ìgbà sì ti kọjá lọ lórí rẹ̀ oi Bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà gbólóhùn tún àlàyé ló máa ń wáyé jùlọ nínú afọ̀ lójú ayé eléyìí náà ni a bá pàdé nínú ewì Aṣọ Ìgbà Gbólóhùn àlàyé ló jẹyọ jù nínú ewì náà ó jẹyọ ni ìgbà ọ̀tàlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹtaódínmẹ́jọ Èyí fihàn pé òǹkọ̀wé lọ àwọn gbólóhùn wọ̀nyí ni àlògbayì èyí tó túmọ̀ sí pé ó ṣe wẹ́kú Bákan náà gbogbo àwọn ọ̀nà èdè bí òwe ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àfiwé àwítúnwí àkànlòèdè àṣọrégèé ìfọ̀rọ̀gbèrọ̀ àti ìfohunpènìyàn tí òǹkọ̀wé lò nínú iṣẹ́ rẹ̀ láti fi ṣe ọbẹ̀ fún àdídùn ló wà ní ìbámu pẹ̀lú ewì kọ̀ọ̀kan ni bí tí wọ́n jẹyọ Bí àpẹẹrẹ a rí bí òǹkọ̀wé ṣe ṣe àmúlò àwítúnwí ẹlẹ́yọọ̀rọ̀ tí ó sí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ibi tí o tí ṣàmúlò rẹ̀ Ó rántí ọjọ́ Ó rántí ìgbọ̀dọ́ ẹ̀ Ó rántí ọjọ́ ti ń bẹ lọ́lọ́mọge Ó rántí gbà tọ́dọ̀ọ́mọkùnrin Ó rántí ọjọ́ tó ni fẹ̀ẹ́ ọlọ́mọkùnrin jọ́gọ́lọ́ oi Bí òǹkọ̀wé ṣe lo àwítúnwí yìí ó lọ daada nítorí ó ń ṣe ìtẹnumọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ó rántí láti ṣe ìṣítí fún ẹnì tí ó ń dojú ọ̀rọ̀ kọ àti láti jẹ kí ọ̀rọ̀ náà ni igbọ́kànró tí ó sì múnilọ́kàn ni Síwájú sí òǹkọ̀wé tún ṣàmúlò àfiwé tààrà lọ́nà tí ó jẹ pé o bá ohun tí òǹkọ̀wé ń ṣe àpèjúwe rẹ̀ mú kí òǹkàwé lè ní òye ohun ti ó ń sọ Àpẹẹrẹ èyí ni a rí nígbà tí òǹkọ̀wé ṣe àfihàn bí àwọn mùsùlùmí ṣe máa ń dìde kúrú tí wọ́n ba n kírun Ó ní Bá wọn jànmọ́ọ̀n tí ń forí kanlẹ̀ Ní wọ́n ń narùn sókè Wọ́n ń ṣe bí adìẹ mumi Lágbada oi Ní ìtẹ̀síwájú bí àkọlé ewì yìí ṣe jẹ́ òwe náà ni a rí ìjẹyọ òwe yìí náà nínú ewì Aṣọ Ìgbà tí òǹkọ̀wé sí ṣàmúlò rẹ̀ lọ́nà tó gbayìn Bí àpẹẹrẹ ewì tí òǹkọ̀wé pé ni Àgbà Kú jàǹbá ṣèlú a rí i pé gbogbo ewì yìí láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ni òǹkọ̀wé fi òwe ṣe ọjọ́ sí lára tí ó sì jẹ́ kí a mọ̀ pé ọmọ ọ̀dọ̀ àgbà ni òǹkọ̀wé ewì Aṣọ Ìgbà jẹ́ ó ni Àwọn àgbà kan àgbà kàn Ló mẹ́nu lọ́rọ̀ o jàre Wọ́ lágbà ó sí Ìlú ṣe bẹ́ẹ̀ ó bàjẹ́ Baálẹ̀ ilé kú Ilé ṣe bẹ́ẹ̀ ó dahoro Bọ́mọdé ń gégi nígbó Àgbà ní mọlẹ̀ tí ó sùn oi Èyí fihàn kedere pé òwe tí òǹkọ̀wé lọ láti fi wa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ara wọn Èyí nìkan kọ́ gbogbo ọnà èdè yòókù náà ló ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìlò rẹ̀ nítorí náà a wá lè sọ pe òǹkọ̀wé kò fi kẹ̀kẹ́ ṣáájú ẹsin nínú bí ó ṣe ṣe ìgbékalẹ̀ àwọn wúnrẹ̀nèdè tó wà nínú ewì rẹ̀ Aṣọ Ìgbà ORÍ KARÙNÚN ÌFÚNÍTUMỌ̀ ÌFÁÀRÀ Ní ibí ganan ni gbogbo àwọn èròjà tí a ti ń mẹ́nubà láti ẹ̀yìn wà yóò tí ni ìtumọ̀ kíkún Òdiwọ̀n yìí náà jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn òdiwọ̀n márùnún tó wà fún ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ lítíréṣọ̀ pẹ̀lú tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè Ní abẹ́ òdiwọ̀n yìí ni onímọ̀ ìṣọwọ́loèdè yóò ti fún afọ̀ tí ó ń yẹ̀wò ni ìtumọ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé kókó leegun iyán ṣùùkù leegun àgbàdo kí á sọ̀rọ̀ kí á ba bẹ́ẹ̀ leegun òótọ́ Kí iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ni ìtumọ̀ aṣeégbà náà ni à pé ni eégún rẹ̀ èyí ni pé ìtumọ̀ ti iṣẹ́ aṣafọ̀ kan bá ni ni yóò jẹ́ kí irú ìwé bẹ́ẹ̀ jẹ́ aṣeégbà láwùjọ àwọn iṣẹ́ lítíréṣọ̀ Èyí túmọ̀ sí pé iṣẹ́ ọ̀nà gbọdọ̀ ni ìtumọ̀ kí á tó lè sọ pé ó kógo já Ìfúnnítumọ̀ yìí ni yóò fún wa láyé láti lè bèèrè pé èèṣe tí òǹkọ̀wé fi gbé ìwé rẹ̀ kalẹ̀ bí ó ṣe gbé e kalẹ̀? Àti pé kí ló gbé e kalẹ̀ fún? Àwọn wo ló ń bá wí? Àwọn wo ló ń bu ẹnu àtẹ lù? Àwọn wo ni ó ń yìn? Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ tilẹ̀ ni nǹkankan ṣe pẹ̀lú àwùjọ bí? Lọ́nà wo? Gbogbo àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni ìfúnnítumọ̀ kúnjú ìwọ̀n láti pèsè ẹ̀sì sí Ìtumọ̀ ló máa ń gbé iṣẹ́ ọ̀nà nìyí Òun ló máa ń jẹ́ kí ó ní ìtumọ̀ tí kì í jẹ́ kí ó já sí òtúbántẹ́ Dájúdájú bí a bá gbé iṣẹ́ ọ̀nà kan yẹ̀wò dandan ni kí ó ní ìtumọ̀ torí pé kò sí òǹkọ̀wé tí ń kọ̀wé e rẹ̀ lórí aṣán Nítorí náà ìtumọ̀ kó ipa tó kira nínú iṣẹ́ ọ̀nà ÌLÀNÀ FÚN FIFÚN IṢẸ́ ỌNÀ NI ÌTUMỌ̀ Bí a ò bá fún iṣẹ́ ọ̀nà kan ni ìtumọ̀ oríṣìí ìtumọ̀ mẹ́ta pàtàkì ló jẹ onímọ̀ ìṣọwọ́loèdè lógún Àwọn ni yóò ṣi ràn wá lọ́wọ́ láti lè fún iṣẹ́ náà ni ìtumọ̀ tó kúnjú ìwọ̀n tó sì pé ye Àwọn ìtumọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni ìtumọ̀ tààrà ìtumọ̀ àkànlò àti ilé gbaìtumọ̀ tàbí ìṣafọ̀ditẹni Ìtumọ̀ tààrà ni ìtumọ̀ tó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká tí tawotọ̀gbẹ̀rì lè fún iṣẹ́ ọnà kan irú ìtumọ̀ báyìí kì í farasin rárá Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ bí a bá wòye títí tí a sọ pé ó mà ṣe o Bọ́lá ti dajá sí ìgboro nínú gbólóhùn yìí a lè fa ọ̀rọ̀orúkọ ajá yọ láti ara ọ̀rọ̀ìṣe dajá kí a sì wo ìtumọ̀ tààrà tí ó ní Gẹ́gẹ́ bí àbùdá àdáni Ajá A lè sọ wí pé ajá jẹ́ ọ̀rọ̀orúkọ ẹranilé kan tó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin ojú méjì ó máa ń gbó tàbí ó ń bu ènìyàn jẹ ó máa ń jẹ ìgbẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ oníṣekúṣe Nítorí náà a ó máa wò ó pé Bọ́lá ti yíra padà di Aja ìgboro tí ń jẹ ìgbẹ́ tí ń gbó tí ń bu ènìyàn jẹ ó sì ti di ẹranko pẹ̀lú Ìtumọ̀ àkànlò èyí ni ìtumọ̀ tó farasin onímọ̀ ìṣọwọ́loèdè ní láti ronú jinlẹ̀ dáadáa kó tó lè fa irú ìtumọ̀ yìí yọ nítorí ó gbọdọ̀ ní àṣomọ́ pẹ̀lú afọ̀ tí a ń yẹ̀wò Àpẹẹrẹ kan náà tí a ó tún lò ni Bọ́lá ti di ajá sí ìgboro nínú ìtumọ̀ àkànlò ohun tó ń bẹ lẹ́yìn ọ̀fà ju òje lọ Pé ajá ni Bọ́lá nínú àyọlò yìí lè túmọ̀ sí igba ọ̀nà Àkọ́kọ́ tí a bá fẹ́ máa ń wo àwọn àbùdá ajá lọ́kọ̀ọ̀kan tí a sì fi Bọ́lá wé ajá tí jẹ̀gbẹ́ a lè sọ pé Bọ́lá jẹ́ ẹnìkan tí ìwà burúkú wà lọ́wọ́ rẹ̀ tí ó sì jẹ́ pé gbogbo nǹkan ìdójú ti ni gbogbo ọwọ́ rẹ̀ ló kún sí Bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ pé gbogbo ìhùwàsí àti ìṣeṣí rẹ̀ kò yàtọ̀ sí ti ẹranko Gbogbo èèyàn ni Bọ́lá ń gbójú mọ́ bí ajá dìgbòlugi Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwà àgbèrè tí ó jẹ́ àbùdá ajá náà ni ó kún ọwọ́ Bọ́lá Gbogbo ohun tí èyí túmọ̀ sí ni ìṣekúṣe A rí wí pé ń ṣe èyí láti tàbùkù Bọ́lá látàrí àti bẹnu àtẹ́ lu ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ kí àwùjọ lè gún régé A sì lo àyọlò yìí láti ṣe pàṣán fún Bọ́lá kí ó ba à lè ti ọwọ́ ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ bọlẹ̀ kí ó sì ṣe àtúnṣe tó yẹ Ìlègbàtumọ̀ tàbí ìṣafọ̀ di tẹni ni kí onímọ̀ ìṣọwọ́loèdè fún afọ̀ tó ní yẹ̀wò ní ìtumọ̀ tó bá òye rẹ̀ mu tó sì ní àṣomọ́ pẹ̀lú àkóónú inú afọ̀ ọ̀hún Fún àlàyé kíkún ẹ jẹ́ kí a lo àpẹẹrẹ Bọ́lá ti dajá sí ìgboro Pẹ̀lú àyọlò yìí gbankọgbì ìtumọ̀ lóríṣìíríṣìí ni a lè fún un Èkínní ni pé Bọ́lá jẹ́ onírìnkurìn ọmọ tí ìdí rẹ̀ kì í mọ́lé Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgbà máa ń sọ pé ibi tí a bá fi ẹlẹ́mọ̀ṣọ́ sọ́ ní ó máa ń sọ́ ṣùgbọ́n ní ti Bọ́lá kainkain ilé tirẹ̀ kì í ta á pàápàá Àfi kí ó máa tojú bọlé onílé kiri Bákan náà a tún lè sọ pé Bọ́lá ti di oníṣekúṣe tí ṣìná tí jàrábà ẹ̀mí rẹ̀ ohun ò ka ọ̀rọ̀ àgbà sí mọ́ pé ohun tó yẹni ló yẹni ìwà àgbèrè ọkọ kan ò kún kọ́ńbọ́ọ́dù kò yẹ omidan ọlọ́mọge ìbànújẹ́ ọjọ́ ọ̀la ló ń fi ṣeré tí yóò wami lójú títí tí kò sì nírí Nítorí náà báyìí gẹ́lẹ́ ni a ó ṣe gbé ìtumọ̀ ewì Aṣọ Ìgbà wò láti lè fún un ní ìtumọ̀ tó mọ́yán lórí tí kò sì lè fa ìkùnsínú kankan láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni ÌTUMỌ̀ TÀÀRÀ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ Ìtumọ̀ tààrà ni fífi àwọn ewì tí òǹkọ̀wé kójọ sínú afọ̀ tí à ń yẹ̀wò sọ ìtumọ̀ tí ewì náà ní Nínú ewì Aṣọ Ìgbà tí a gbé yẹ̀wò yìí a ṣàkíyèsí pé òwe ni òǹkọ̀wé fi ewì Aṣọ Ìgbà pa Gbogbo àlọ́ àti ààlọ̀ inú ewì náà ni ó jẹ́ kìkì òwe Èyí tí ó jẹ́ ọ̀nà tí Yorùbá fi máa ń sọ̀rọ̀ nítorí pé ìran Yorùbá kì í sàdédé la gbogbo ẹnu sọ̀rọ̀ àfi kí wọ́n máa ṣàmúlò àkàwé láti fi sọ ohun tí wọ́n ní lọ́kàn látàrí àti kọ́ni lọ́gbọ́n kan tàbí òmíràn Nígbà tí a ṣe ìtúpalẹ̀ ewì náà òwe ni òǹkọ̀wé ń fi àkọlé ewì náà pa Òwe yìí náà ni Aṣọ Ìgbà tí à á dá fún ìgbà Pẹ̀lú òwe yìí a rí i pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé ìran Yorùbá ní onírúurú aṣọ tí wọ́n máa ń ṣàmúlò nígbà tí ilẹ̀ bá tutù bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbà ọ̀gbẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ní aṣọ ìmúròde aṣọ iṣẹ́ àti aṣọ tí ń fi ń sùn nínú ilé Òde tí wọ́n bá sì ń lọ ni yóò sọ irú aṣọ tí wọn yóò wọ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú ewì náà a rí i wí pé ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojúmọ́ tí ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ ni òǹkọ̀wé kójọ sínú ìwé rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà kan lọ ìgbà kan ń bọ̀ ìgbà kan ò sì lo ilé ayé gbó Bẹ́ẹ̀ náà ni ohun tí òǹkọ̀wé ewì Aṣọ Ìgbà ń sọ a rí àpẹẹrẹ ìgbà tí àwọn Ẹgbẹ́ Olùkọ́ ÁSÙ ń jà fún àwọn òṣìṣẹ́ olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ a rí i pé ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò pẹ́ púpọ̀ ni tí ó sì wá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ akadá tí ń ṣe olùkọ́ ni ó máa ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti jẹ́ kí àwọn ọmọ ọlọ́mọ tí wọ́n ń kọ́ di èèyàn ńlá àti èèyàn iyì láwùjọ Ṣùgbọ́n tí ọ̀rọ̀ wọn wá di iṣẹ́ larí a ò rówó gbogbo wọ́n wá ṣíṣe bí erin wọ́n ń jẹ ìjẹ ẹ̀lẹ́rí A rí i pé erin jẹ́ ẹranko tí ó tóbi tí ó sì lágbára púpọ̀ fìrìgbọ̀n rẹ̀ lásán tó bani lẹ́rù Ṣùgbọ́n wọ́n wá ń gba owó tí kò tó ẹ̀lẹ́rí eku kékeré jẹ tí ó sì wa jẹ́ pé owó ni iyì ìwé ní àsìkò tí a wà yìí kì í ṣe ìmọ̀ ìwé mọ́ Bí àpẹẹrẹ nínú ewì ÁSÙ Fọnmú òǹkọ̀wé sọ báyìí pé; Bakadá tí ń fìmọ̀ bọ́mọ olówó Lakadá ń fìmọ̀ bọ́mọ òtòsì Àtọmọ ọlọ́lá àtọmọ mẹ̀kúnnù Gbogbo wọn pátá lakadá ń kọ́ papọ̀ Kò ṣágbà nígbó ọ̀kẹ́rẹ́ lọ̀rọ̀ ìwé Bí kóówá bá ti nímọ̀ nìwé Agbówókaríowóná nìyá mi Kì í sọ̀rọ̀ ìwé rárá Owótabua ni bàbá mi ni Kì í soro ìmọ̀ ẹ̀kọ́ pàápàá oi Bákan náà nínú ewì yìí ni a tí rí ohun ìgbàlódé tí ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọba ilẹ̀ Yorùbá nítorí ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ kò sí ohun tí ọba ṣe tí kò ṣegbé bẹ́ẹ̀ sì ni ọba máa ń dúró bí èkejì òrìṣà ni Gbogbo ohun tí wọ́n bá ti sọ ni àṣẹ gùn Bẹ́ẹ̀ sì ni ní ilẹ̀ Yorùbá bí ó ba kan ò kú òmíràn ò le jẹ́ ní ṣùgbọ́n ní ti ìgbàlódé gbogbo nǹkan ti yípadà ohun tó bá wu olóṣèlú ni wọ́n ń ṣe Irú rẹ̀ ni òǹkọ̀wé fihàn nínú ewì tí ó pè ni Kábíyèsí tí ó sọ báyìí pé; Ọ̀rọ̀ tí doódì Èsúró pàdí dà Ó ń lájá ọdẹ Ọ̀wọ̀ ò sí fórí adé mọ́ Ipò ọba dohun àmúṣeré Ipò aláyélúwà ti dohun ẹ̀fẹ̀ Ayé ọba aládé ti dohun yẹpẹrẹ oi Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú ewì náà a rí i wí pé òṣèlú ìgbàlódé tí ìjọba tiwańtiwa láyé Bàbáńgídá tí ó yọ ọba Sultan ti Sókótó Dansuki kúrò lórí oyè lọ́nà àìtọ́ pẹ̀lú ẹjọ́ kò tẹ́milọ́rùn iléẹjọ́ ọ̀hún ni tí ó sì fi òmíràn jẹ bẹ́ẹ̀ náà ni tí ÀtàỌjà tilẹ̀ Òṣogbo tí iléẹjọ́ dájọ́ ìyọkúrò rẹ̀ lórí oyè baba wọn A rí i pé èyí tako èrò ìjìnlẹ̀ Yorùbá pé bí ọba kan ò tí ì kú òmíràn ò lè jẹ ṣùgbọ́n nǹkan ti yí padà Ajá ló yẹ kí ó máa lé èsúró ní àtètèkọ́ṣe ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ Orí ti dìrù ìrù ti dorí Ẹni iwájú ti wá di ẹni ẹ̀yìn Òjò ti pàlàpà ó di àmúgùn féwúrẹ́ Ipò ọba ti di yẹpẹrẹ tí àwọn olóṣèlú ìgbàlódé mú gùn bí ẹsin Èyí ló sì mú òǹkọ̀wé gba àwọn ọba nímọ̀ràn kí wọ́n tẹ̀ sibi ayé tẹ̀sí kí wọ́n má ba à jìyà Kí adé lè pẹ́ lórí kí bàtà lè pẹ́ lẹ́sẹ̀ kánrin kése Kírùkẹ̀rẹ̀ ba à pẹ́ lọ́wọ́ Bákan náà bí a bá tún wo àwùjọ òdeòní a rí i pé kì í ṣe ohun tí olúkúlùkù lọ kà ni ó fi ń ṣiṣẹ́ tí ó sì fi ń rówó náà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ṣe bí ohun tí ó bá ka ní iléìwé ni ó máa fi ṣiṣẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni bí ó bá ti ń ṣe tán báyìí ni wọn yóò ti máa wa fún àwọn ti ń jáde kí wọ́n lè gbà wọ́n ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n ní àsìkò bágbàmu tí a wà yìí A rí i pé èsúró ti pàdí dà ó ń lájá ọdẹ Gbogbo rẹ̀ ti yípadà Èyí ganan ni ó jẹ́ kí ètò ẹ̀kọ́ orílẹ̀èdè wa wa lẹ́yìn nígbà tí ó jẹ́ pé àti ẹni tó kàwé dójú àmì àti ẹni tí ó kà dójú àmì ní ṣiṣẹ́ olùkọ́ Òun ló gba ọ̀lẹ tó tún gba dọ́kọdọ́kọ Èyí ni òǹkọ̀wé là hàn wá nínú ewì Bí iṣẹ́ Tíṣà kọ́ ó lọ báyìí; Bá a bá ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ òòjọ́ Ó lójú iṣẹ́ tà á ń wí Bi iṣẹ́ tíṣà kọ́ là ń sọ Iṣẹ́ tí tajá tẹran ń ṣe Bó ò kírun bó ò kírun Nìṣó ní mọ́sálásí níṣẹ́ olùkọ́ Àtẹni kọ́ṣẹ́ olùkọ́ Àtẹni tí kò nímọ̀ nípa iṣẹ́ tíṣà Gbogbo wọn ni wọ́n luṣẹ́ olùkọ́ pa Iṣẹ́ olùkọ́ wá di dańdawì Iṣẹ́ tíṣà wá di wọ́lùkọlù Gbogbo ènìyàn tó ti fẹsẹ̀ roko ìlú ká Iṣẹ́ tíṣà làbọ̀ábá oi Síwájú sí i tí a bá wo àwùjọ wa lónìí a rí i pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin tí kòju píníṣín lọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé iléìwé gíga ló jẹ́ pé ohun tí wọ́n bá wá sí iléìwé ti di àpatì bí aṣọ eégún tí ó sì jẹ́ pé àwọn bàbá olówó ni gbogbo wọn ń bá kiri gbogbo ohun tí wọn ò lè ṣe nígbà tí wọ́n wà nílé lọ́dọ̀ òbí wọn ni wọ́n ń dánwò báyìí Wọn ti gbàgbé òwe Yorùbá tó sọ pé a kì í léku méjì ká má pàdánù ọ̀kan Èyí ìwé tí ó yẹ kí wọ́n gbajúmọ̀ wọ́n ti fi ṣe ọ̀fà dànù èyí ẹ̀kọ́ tó yẹ kí wọ́n múra sí gidigidi kí wọ́n máa ba pàdánù ọkùnrin ni wọ́n kọ́jú mọ́ Irú èyí ni òǹkọ̀wé fihàn nínú ewì Sisí Akadá bayi; Pẹ̀lẹ́ o sisí akadá À ṣẹ̀ṣẹ̀ jánà agódòńgbó Ọlọ́un ó ṣe jùyá òun Gàlègàlè rẹ yìí kò a pọ̀jù Là á pọ́dún kan tán O tí pàrọ̀ akọ tó mẹ́wàá Kọ́ọ̀sì mẹ́rin ṣàǹkò Lọ forí ṣánpọ́n ní ṣimẹ́sítà kìíní A kì í múṣẹ́ jẹ Ká múyà jẹ Sisí akadá Ìwé kíkà lodùn oi Òǹkọ̀wé lo ewì yìí láti sọ fún ọmọge àsìkò kí wọ́n síwọ́ oge àṣejù tí ò lè gbé wọn dé ibì kankan ṣùgbọ́n bí wọ́n bá gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ wọn yóò sọ wọ́n dọ̀gá Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣátá ẹ̀kọ́ ohun tó yẹ ọmọge tó gbọ́n ni kí ó múra láti ṣiṣẹ́ takuntakun kí wọ́n máa ba fi igbe ohun òṣé lo ìgbẹ̀yìn ayé wọn kí wọ́n dín fulenge fulenge wọn kù kí wọ́n gbajúmọ̀ ẹ̀kọ́ tó ṣe kókó fún wọn báyìí Ní ṣókí ìtumọ̀ inú ewì Aṣọ Ìgbà ni ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ tí ó dára tẹ́lẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ṣùgbọ́n tí àsìlà ojú ti wá sọ ọ́ di ìdàkudà ní àwùjọ wa Bẹ̀rẹ̀ láti àwọn olórí orílẹ̀èdè títí dé ọ̀dọ̀ ọmọ pínsíní ÌTUMỌ̀ ÀKÀNLÒ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ Ìtumọ̀ tó farasin ni ìtumọ̀ àkànlò ó gba ìrònújinlẹ̀ onímọ̀ ìṣọwọ́loèdè Pẹ̀lú àríwòye wa a rí i pé ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ tàbí ọ̀rọ̀ tí a le pè ní àkànlò èdè ni òǹkọ̀wé fi ṣe àkọlé ewì rẹ̀ èdè àsìkò ni Aṣọ Ìgbà nínú àwùjọ àwọn èdè kan wà tó jẹ́ pé àṣà àsìkò ni ó máa ń bí wọn Lára irú àwọn èdè náà ni Aṣọ Ìgbà o ò wọ àǹkárá o ò jẹ sẹ̀mó o ò wọ gínnì o ò gba ke Nǹkan tí à ń gbìyànjú láti sọ ni pé bí àṣà kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọjú sí àwùjọ kan ó di dandan kí èdè tó jẹ pé irú àṣà bẹ́ẹ̀ mú yọjú bí o tilẹ̀ jẹ́ pé irú èdè bẹ́ẹ̀ tilẹ̀ wà tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n kí àwọn ènìyàn inú àwùjọ máa fún un ní ìtumọ̀ ti àṣà yẹn fún un Gẹ́gẹ́ bí èrò ìjìnlẹ̀ àwọn Yorùbá pé àìrìnjìnnà la ò rábuké ọ̀kẹ́rẹ́ bí a bá sì rìn jìnnà oríṣìíríṣìí àṣà ìgbàlódé tó bójúmu àti èyí tí ò bójúmu la ó máa rí Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí nínú ìṣeṣí àti ìhùwàsí Yorùbá láti máa hùwà ọkọ kan ò kún kọ́ńbọ́ọ̀dù ṣùgbọ́n a rí èyí nínú ìṣeṣí àwọn ènìyàn tí wọ́n gbé e wọ̀ bí ẹ̀wù látàrí àti sọ ọ́ di àṣà àwùjọ Òǹkọ̀wé jẹ́ ká mọ̀ pé kò sí èrè nínú gbogbo ìwà játijàti tó kún ọwọ́ ọmọdé àti àgbàlagbà wọ̀nyí Nítorí bí ọwọ́ pálábá wọn bá sẹ́gi ìtìjú àti ìbànújẹ́ ọjọ́ iwájú ni wọ́n fi ń ṣeré tí wọ́n sì ń fi ọjọ́ ọ̀la wọn tayò Nítorí ohun tí oníkálùkù bá gbìn ni yóò ká Ẹni gbin ìwà búburú ìwà rẹ̀ yóò padà bá a ẹni tí ó sì gbin ìwà rere rere ni yóò padà ba Gbogbo nǹkan ló sì lẹ́san tí yóò fún oníkálùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ Ìtumọ̀ àkànlò tí a kọ́kọ́ lè fún àkọlé ewì Aṣọ Ìgbà yìí ni bí àkọlé ìwé náà ṣe bá ìhùwàsí àti ìṣeṣí àwọn tí òǹkọ̀wé ṣàmúlò nínú ewì náà ṣe báwọn mu Bí àpẹẹrẹ a lè fi aṣọ ìgbà wé ìwà Bẹ́wàjí òṣèlú òde òní gbéborùn àgbèrè ìmẹ́lẹ́ jẹgúdújẹrá tí ó sì jẹ́ ti àsìkò tí a wà yìí gbogbo ìwà búburú wọ̀nyí ni àwọn ọmọdé àti àgbàlagbà gbé wọ̀ bí ẹ̀wù ti wọ́n fi ń ṣe aṣọ iyì kiri àwùjọ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé a máa mú aṣọ wọ̀ bora ni bẹ́ẹ̀ ni àwọn Bẹ́wàjí òṣèlú alágbádá àti ológun náà mú ìwà jẹgúdújẹrá bora bí aṣọ àsìkò Irúfẹ́ ìwà yìí ni a rí nínú ewì Ṣáágo ń Búgò ó ní; Ṣe bí àjẹwẹ̀yìn ni talágbádá Wọ́n kì í gbàgbé àti fọ́n díẹ̀ díẹ̀ Àmọ́ ní talágbádá àjẹ̀ tán ni oi Bákan náà òǹkọ̀wé jẹ́ kí a mọ̀ pé ṣe é lẹ̀ ni ń jẹ́ ṣe é bá Gbogbo ohun tẹ́dàá sì ṣe ni ó ní èrè nínú gbogbo ọmọge tí kun ìkùn kikùn nítorí à ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin balẹ̀ nípasẹ̀ ìṣekúṣe tí ó ti jàrábà ẹ̀mí wọn tí wọ́n sì ti sọ di aṣọ ìmúròde Irúfẹ́ rẹ̀ ni a rí nínú ewì Ẹ̀lẹ̀ Òṣíẹ̀lẹ̀ ó ní; Ẹ̀lẹ̀ tó ó lọ́wọ́ ẹ̀lẹ̀ òsíẹ̀lẹ̀ Rọra máa jọ̀fẹ́ fẹ̀ẹ́ fẹ̀ẹ́ kiri ayé Àìjọ̀fẹ́ ká má fẹ̀yìn ralẹ̀ fákọ lálẹ́ Kó fi pàmúkùrú pẹ̀lẹ́ Ẹ̀lẹ̀ òṣíẹ̀lẹ̀ ti fìkánjú bọjọ́ alẹ́ jẹ́ Níbi a ń sán lẹ́bẹ́ aṣọ kiri oi Lẹ́yìn gbogbo òwò ṣìná tí wọ́n ti ṣe Nígbà tí wọ́n bá wa di onídìlé wọ́n yóò wá ní pé ìyá ọkọ wọn ni ò jẹ́ kí wọ́n rọ́mọ bí tàbí ìyá àti bàbá kan láagbo ilé wọn ló ń ṣe wọn Ẹ̀yìnòrẹyìn wọ́n ò wà ní ìfọ̀kànbalẹ̀ Ohun tí ó yẹ kí wọ́n ṣe lówùrọ́ọ̀ wọ́n yóò wá máa ń ṣe ní alẹ́ Òǹkọ̀wé tún fọgbọ́n sọ̀rọ̀ lọ́nà àkànlò wí pé ó sòro láti mọ ẹni ibi nítorí ayé tí dojú méjì ọmọ ń gbé ìyáa rẹ̀ tà bẹ́ẹ̀ ni baba ń gbé ọmọ rẹ̀ sògùn owó ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ Ọlọ́run ni ń kó ẹ̀dá yọ nínú àjàgà ayé Irúfẹ́ èyí ni òǹkọ̀wé fihàn nínú ewì Imúníkà Ó ní; Bímú ti wá gbóòórùn tó Imú kò gbóòórùn abínúẹni Imú rí kánńbó lásán ni Kò le è ṣàfihàn ìkà èèyàn Bímú bá mọṣẹ́ ẹ̀ dọba Òréré là bá ti yẹra fólubi oi Yàtọ̀ sí èyí òǹkọ̀wé tún fọgbọ́n ṣe ìwàáṣù pé ikú ni èrè ohunkóhun tí ẹ̀dá bá gbé ilé ayé ṣe Ó fi kún un pé àti alágbára àtolówó ayé àtọlọ́lá àtolòsì nikú ó pa Kí gbogbo mùtúmùwà dín fulenge kù Nítorí bí ayé ṣe ń yí bí a bá ba lọ báyìí gbogbo nǹkan kò ní pẹ́ dàrú kí ó sì dohun ìbànújẹ́ Ìwà ọmọlúàbí ló yẹ ọmọ ènìyàn ohun tí ọwọ́ ò bá sì tó kò yẹ kí a fi gọ̀ọ̀gọ̀ fà á dandan Nítorí gbogbo kọ́bí kó sọ̀hún ikú lòpin ohun gbogbo nílé ayé kò sí bí ènìyàn ṣe lè pẹ́ tó yóò kú náà ni àti aṣebi àti aṣèkà gbogbo kálukú ni yóò jíyìn ohun tó gbélé ayé ṣe Irúfẹ́ rẹ̀ ni òǹkọ̀wé fi kọ ewì pé Ọpẹ́ PElédùmarè dákú Látàrí àti kíyèsí gbogbo ìwà ìbàjẹ́ wọ̀nyí tí wọ́n fi ṣe aṣọ àwùjọ kì í ikú tó dé Ó ní; Gbogbo ọmọilé ti ń sọ̀tẹ̀ baálé Ikú lèrè ohun gbogbo Ọpẹ́ pElédùmarè ti fikú ṣọ̀gá Kí gbogbo ṣìkàṣìkà rántí pé ṣáà làá ni Ẹnìkan ò ni gbogbo ìgbà Ìgbà kan ò sì lo ilé ayé gbó Iléayé àlòpatì Àbáfisílẹ̀ nílé ayé Kíkú ire ó pani lọ́jọ́ alẹ́ oi ÌṢAFỌ̀ DI TẸNI EWÌ AṢỌ ÌGBÀ Òfin yìí kan náà ni a tún ń pè ní ìlégbàtumọ̀ Ibí ganan ni a ti máa sọ àsọyán kàìnkàìn lórí ewì tí à ń yẹ̀wò Gẹ́gẹ́ bí àkíyèsí mi mo rí i pé ewì akọ́nilọ́gbọ́n ni ewì Aṣọ Ìgbà yìí àti pé ó tún jẹ mọ́ àwùjọ pàápàá jùlọ àwùjọ tí òǹkọ̀wé kọ ewì yìí fún àwùjọ Yorùbá kì í ṣe ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àdúgbò kan tàbí agbègbè kan ni ewì yìí àríwòye òǹkọ̀wé nípa nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ wa lásán ni òǹkọ̀wé kàn fi ọgbọ́n àtinúdá gbé kalẹ̀ sínú ìwé kan kì í kúkú ṣe pé gbogbo nǹkan tí òǹkọ̀wé kọ sínú ewì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ ṣe àjòjì sí wa Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìwà ọkọ kan kò kún kọ́ńbọ́ọ̀dù títi orí ọkùnrin kan bọ́ sí èkejì àti àwọn ìwà pálapàla mìíràn gẹ́gẹ́ bí a ṣe bá wọn pàdé lọ́wọ́ Bẹ́wàjí nínú ewì Lẹ́tà sí Ẹwà Lásìkò kan náà Bẹ́wàjí tún ń nájà Pẹ̀l àwọn baálé ilé mẹ́rin Láì jẹ́kìnínní kejì mọrawọn Tí wọ́n ti wínra nínú òwò ṣìná oi Àkọlé mìíràn tí mo lè fún ewì yìí ni Èrè Àgbèrè Bákan náà gbogbo ìwà àwọn olórí àwùjọ ni òǹkọ̀wé fihàn tí ó sì jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ rí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òǹkọ̀wé ṣe àtinúdá tirẹ̀ láti kọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ papọ̀ kí a tó pè é ní ewì a wòye pé òǹkọ̀wé ń gbìyànjú láti gbé sí àwùjọ ni pé ohun tí ó wà lẹ́yìn ọ̀fà ju òjé lọ fún ẹni tí ó bá báwọn dá aṣọ ìgbà tí inú rẹ̀ ń dùn Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Yorùbá pé àgùntàn tóbá bájá rìn yóò jẹ̀gbẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni tí ò ní ìyá kì í dégbò ẹ̀yìn Ẹni tí ó sì ṣe ohun tí ẹnìkan ò ṣe rí dandan ni kí ojú rẹ̀ róhun tẹ́nìkan ò rí rí Ẹni tí ó bá wọn dáṣọ ìgbà ohun ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò dà ni afàgò kẹ́yin àparò ohun ojú wá lójú rí Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ ṣáájú pé ewì akọ́nilọ́gbọ́n asíniníyè ni ewì Aṣọ Ìgbà Ẹní tó bá ka ewì yìí yóò kọ́gbọ́n pé àbámọ̀ ní kẹ́yìn ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ kíkó Yàtọ̀ sí èyí ewì yìí tún jẹ́ kí a mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ejò ni jíjẹ Nítorí ẹni tí ó bá jẹ́ pé ó fẹ́ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ni agbègbè tàbí ní àgbáyé tí kò ṣe bí ó ṣe mọ ẹ̀wù ẹ̀tẹ́ ohun àbùkù ni yóò wọ̀ bọ̀ Pẹ̀lú ìtumọ̀ tí ewì Aṣọ Ìgbà yìí ní sí mi ìtumọ̀ mìíràn tí a lè fún un ni Ayé ń Yípo Ìdí ni pé gbogbo nǹkan ló ti yípadà sí ti atayébá lásìkò yìí ètò ìṣèlú ti forí ṣánpọ́n ọmọ ènìyàn wá sọra wọn di kàlòkàlò tí ń gbówó mì Bẹ́ẹ̀ ni ètò ẹ̀kọ́ ti di àfìsẹ̀yìn téégún fiṣọ Ìwà ọmọlúàbí tí gbogbo ènìyàn làkàkà láti jẹ́ wá di àtẹ̀mẹ́rẹ̀ oníkálùkù wá ń gbé ìgbé ayé kò kàn mí tani yóò múmi kóńkó jabele kálukú ni ṣe tirẹ̀ Èyí tí yóò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ kábàámọ̀ lọ́jọ́ iwájú pẹ̀lú ẹkún kíkorò èyí sì le púpọ̀ ORÍ KẸFÀ ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ ÌFÁÀRÀ Àwọn Yorùbá bọ̀ wọ́n ní akii ya àwòrán gàgàrà kí a má fi tì síbì kan Láti kádìí iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ ewì Aṣọ Ìgbà nílẹ̀ a máa wo àmúyẹ àti àléébù ewì Aṣọ Ìgbà ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí A máa sọ ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú Lẹ́yìn èyí ni ó kan ìkádìí níbi tí a ti máa sọ̀rọ̀ ní ṣókí lórí gbogbo àwọn nǹkan tí a ti ń sọ bọ̀ wá láti ẹ̀yìn ÌSỌNÍṢÓKÍ ÀBỌ̀ ÌWÁDÌÍ Ní ìkádìí àgbéyẹ̀wò ìfojú ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè ṣe ìtúpalẹ̀ ewì Aṣọ Ìgbà tí Dúró Adélékè kọ Iṣẹ́ yìí fihàn gẹ́gẹ́ bí akéwì òǹkọ̀wé ewì tí ó ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí tí ó sì ni ìpinnu ọkàn láti di gbajúgbajà láàárín àwọn afèdèsọnà òǹkọ̀wé ewì ẹgbẹ́ rẹ̀ tó kù Pàápàá àwọn òǹkọ̀wé ewì ìgbàlódé Àgbéyẹ̀wò ìlòèdè fihàn gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé ewì tó gbédè gbẹ́yọ̀ Bákan náà kókó inú ewì rẹ̀ fihàn gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ ojú ayé bẹ̀rẹ̀ láti ewì àkọ́kọ́ tí ó pè ní Ẹ̀yìnlàárò títí dé èyí tí ó parí tí ó pè ní Ọpẹ́ PÒdùmàrè Dákú gbogbo rẹ̀ ló gùnlé àṣà ilẹ̀ Yorùbá àti ìṣẹ̀ṣe wọn tí ó sì bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí ó dára ní àwùjọ pàápàá ìwọṣọ ìmukúmu àti àwọn ọmọge tí wọ́n ń tara wọn lọ́pọ̀ torí afẹ́ ayé tí yóò já wọn sílẹ̀ láìpẹ́ Ó sì tún lo ewì yìí láti fi ṣe ìsìtí àti ìmọ̀ràn lóríṣìíríṣìí tí yóò ṣe ènìyàn ní àǹfààní lásìkò tí ayé ti di ojú kejì Síwájú sí i ó yẹ kí a gbé òsùbà fún Dúró Adélékè fún ọ̀nà tí ó gbà gbé ewì rẹ̀ kalẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe àmúlò ọ̀pọ̀ ọnà èdè bí i; òwe àkànlò èdè tí gbogbo rẹ̀ sì múnádóko tí ó sì ṣiṣẹ́ tí ó fẹ́ gbogbo rẹ̀ ṣe láwùjọ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ oríṣìíríṣìí ÀMÚYẸ ÀTI ÀLÉÉBÙ INÚ EWÌ AṢỌ ÌGBÀ Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àmúyẹ iṣẹ́ ọnà kan nǹkan tí a ní lọ́kàn ni àwọn nǹkan tó mú kí ewì náà gbayì tí a fi sọ pé iṣẹ́ ọnà ọ̀hún kúnjú òṣùwọ̀n Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀ àwọn nǹkan tí a lè tọ́ka sí bí i kùdìẹ̀kudiẹ iṣẹ́ ọnà kan ni a máa ń fàyọ gẹ́gẹ́ bí àléébù iṣẹ́ ọnà ọ̀hún Ṣùgbọ́n a fẹ́ kí ó di mímọ̀ fún wa pé kò sí adáramákùsíbìkan Ẹni tí a lè sọ pé iṣẹ́ ọnà rẹ̀ pegedé tó sì fi gbọ̀rọ̀jẹkà ni ẹni tó jẹ́ pé ibi tí iṣẹ́ ọnà rẹ̀ dára sí pọ̀ju ibi tó kù sí lọ ìgbà yìí ni a tó lè sọ pé iṣẹ́ rẹ̀ gbóúnjẹ fẹ́gbẹ́ ó sì gbàwo bọ̀ Ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún wa pé bí ewì Aṣọ Ìgbà ṣe jẹ́ àkọ́já ewé fún òǹkọ̀wé yìí àléébù inú ewì yìí kì í ṣe ohun tí a lè fúnka mọ́ tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ ṣe Yorùbá náà ló kúkú máa ń pa á lówe pé a kì í mọ̀ ọ́n gún mọ̀ ọ́n tẹ̀ kí iyán ewùrà máà lẹ́mọ ó tilẹ̀ yẹ kí a gbé òṣùbà bàǹbà fún Dúró Adélékè fún iṣẹ́ akadá tó jíire tí ó ṣe yìí Bákan náà a tún rí i pé òǹkọ̀wé kò ṣàì ṣe àmúlò àwọn ọnàèdè bí i; òwe àkànlòèdè àfiwé tààrà àti ẹlẹ́lọ̀ọ́ ìfọ̀rọ̀gbeọ̀rọ̀ náà kò sì gbẹ̀yìn níbẹ̀ Àwọn àṣà àti ìṣẹ̀ṣe Yorùbá bí i ọfọ̀ orin tí òǹkọ̀wé ṣe àmúlò nínú ewì náà buyì kún ewì náà ó sì jẹ́ kí òǹkàwé kàá ní àkàgbádùn Wàyíì bí a bá tún fojú sùnùkùn wo ewì yìí a ó rí àwọn ohun sùnùkùn tó ta kókó àbùkù díẹ̀ bá ewì náà tí ó tọ́ka sí àléébù yìí kì í ṣe pé à ń gbìyànjú láti ba iṣẹ́ òǹkọ̀wé jẹ́ tàbí pé a fẹ́ bu ẹnu àtẹ́ lu iṣẹ́ rẹ̀ A kàn fẹ́ pe àkíyèsí òǹkọ̀wé sí àárín yẹn ni kí òǹkọ̀wé lè ṣe àtúnṣe nínú iṣẹ́ rẹ̀ mìíràn tí ó bá tún máa gbé jáde Àléébù tí a rí tọ́kasí nínú ewì yìí kò pọ̀ rárá Àkọ́kọ́ ni àṣìtẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kan nípa àwọn àmì ohùn orí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ní ojú ìwé ó ní; Adẹtẹ̀ tórí wèrè tó méré sá Dípò kí ó jẹ́; Adẹ́tẹ̀ tórí wèrè tó méré sa oi ìlà A tún rí òmíràn ní ojú ìwé ó ní; Pé kó yẹfun tàjà wò Dípò pé; Pé kó yẹ̀fun táyà wò Bákan náà a rí òmíràn ní ojú ìwé ó ní Ká tún lọ máa ṣe màgòmago nídìí òwó Dípò kí ó jẹ́; Ká tún lọ máa ṣe màgòmágó nídìí òwò tàbí owó Bákan náà atun rí òmíràn nínú ewì Oníkàn yìí Rọra níbi tí ìjọba ti ń pè fún ìfọwọ́ṣowọ́pọ̀ a rí pé òǹkọ̀wé ta ko ìṣọ̀kan ti orílẹ̀èdè wa Nàìjíríà ń pè fún nínú ewì Oníkàn yìí Rọra Ó gbà pé ọ̀rànanyàn kọ́ ni àjọṣepọ̀ kí oníkálùkù ẹ̀yà gba agbègbè tirẹ̀ lọ Àtakò pátápátá gbá à ni èyí jẹ́ fún ìpè ìṣọ̀kan tí àwùjọ wa ń pè fún lónìí pàápàá fún ìlọsíwájú ètò ẹ̀kọ́ ìṣèlú àti ọrọ̀ajé wa A rí èyí ní ojúìwé ó ní; Ọ̀fọ́nọ̀n ti tọ̀ ọ́ gbẹ̀gìrì Kẹ́lẹ́kọ kẹ́kọ ẹ̀ lọ́wọ́ Kí kóówá gba sarè e baba ẹ lọ Ọ̀rànanyàn kọ́ làṣepọ̀ Lẹ́yìn àléébù méjì pere wọ̀nyí ewì Aṣọ Ìgbà kúnjú òṣùwọ̀n gẹ́gẹ́ bí ewì àpilẹ̀kọ tí ìgbàlódé tí ó sì jẹ mọ́ àwùjọ Àmúyẹ inú ìwé ewì yìí pọ̀ a kò sì lè tú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ tán èyí ló jẹ́ kí a mọ Dúró Adélékè bí òǹkọ̀wé ewì tó gbédè tó sì mẹ̀wọ́n èdè Èyí ni pé ọ̀kan ni ewì Aṣọ Ìgbà láàrín ogunlọ́gọ̀ ewì àpilẹ̀kọ tó wà láwùjọ ÌMỌ̀RÀN FÚN ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Ìmọ̀ràn wa ni pé a rọ àwọn òǹkọ̀wé ewì kí wọn máa ṣe dẹ́kun kíkọ irú àwọn àkójọpọ̀ ewì báyìí síta nítorí pé irú àwọn ewì báyìí yóò ṣe àǹfààní gidi fún àwùjọ wa Nítorí ọ̀pọ̀ tí ó jẹ́ pé òròjú máa ń ṣe láti ka eréoníṣe àpilẹ̀kọ tàbí ìtàn àròsọ yóò ní àǹfààní láti lè ka ewì àpilẹ̀kọ nítorí ohun kì í ń kún ojú ìwé bí àwọn lítíréṣọ̀ àpilẹ̀kọ tó kùnún Bákan náà a tún gba àwọn oníwàdìí ọjọ́ iwájú ní ìmọ̀ràn láti jẹ́ kí irú iṣẹ́ ìwádìí báyìí dúró Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lè kàn máa ka ewì náà gbuurugbu ṣùgbọ́n kí ó máa rí ẹ̀kọ́ kan gbòógì kọ́ níbẹ̀ Kí èdè tí òǹkọ̀wé ṣàmúlò máa ni ìtumọ̀ ṣùgbọ́n irú ìwádìí báyìí yóò sí ojú àwọn òǹkàwé sí ohun ganan tí òǹkọ̀wé ewì fẹ́ kí wọ́n mọ̀ àti pé yóò jẹ́ kí wọ́n kọ́ ẹ̀kọ́ kan tàbí òmíràn kọ́ Ní àkótán pàtàkì ni ewì àpilẹ̀kọ jẹ́ nínú lítíréṣọ̀ àpilẹ̀kọ Yorùbá ó sì jẹ́ ọ̀nà kan tí a lè lò láti koná mọ́ àwọn àṣà Yorùbá tí ó ti di àfìsẹ́yìn téégún fiṣọ bí ìwà àgbèrè ìwọ̀kuwọ̀ àwọn obìnrin ìhùwàsí àwọn adarí Kí àṣà yìí tí àwọn ọ̀dọ́ òde òní tí ń jẹ́ kí ó ń jọ́ àjórẹ̀yìn le padà bọ̀ sípò kí àtúnṣe sì lè wà láwùjọ wa lórí àwọn ohun wọ̀nyí ÌKÁDÌÍ Mo ní ìgbàgbọ́ pé iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí yóò ran àwọn tó bá ń ṣíṣe lórí ìfojú ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè tú iṣẹ́ lítíréṣọ̀ palẹ̀ ní èdè Yorùbá lọ́wọ́ púpọ̀ Láti kadii iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ ewì àpilẹ̀kọ Aṣọ Ìgbà nílẹ̀ ó yẹ kí á sọ̀rọ̀ ní ṣókí lórí gbogbo àwọn nǹkan tí a ti mẹ́nuba lẹ́yìn Gbogbo àwọn èròjà tí òǹkọ̀wé ewì kó jọ pọ̀ sínú ìwé rẹ̀ ni a ti yẹ̀wò bí; akópa ìṣẹ̀lẹ̀ kókó àti wúnrẹ̀n èdè A wo òdiwọ̀n ìtayọ láti wo bí àwọn èròjà wọ̀nyí ṣe ta ara wọn yọ sí Gbogbo òfin ìtayọ náà ni a sì ṣe àmúlò Bákan náà a wo bí àwọn èròjà wọ̀nyí ṣe bá ara wọn mu sí lábẹ́ òdiwọ̀n ìṣewẹ́kú Èyí nìkan kọ́ a wo ìtumọ̀ tààrà ìtumọ̀ àkànlò àti ìṣafọ̀ditẹni lábẹ́ òdiwọ̀n ìfúnítumọ̀ Ní àkótán gbogbo àwọn èròjà tí òǹkọ̀wé lò nínú iṣẹ́ rẹ̀ ló múnádóko ó sì fihàn bí akadá tó gbọ́fèé Nítorí náà a ní ìrètí pé àpilẹ̀kọ yìí yóò jẹ́ àrídájú pé a kò le fojú rénà ìlòèdè kúrò lára ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ÌFOJÚ TÍỌ́RÌ ÀṢÀ ÌBÍLẸ̀ WO ÌWÉ ERÉONÍTÀN ÀGBÀ TÍ Ń YỌ́LẸ̀ DÀ TÍ OLÚ OWÓLABÍ KỌ AKÍNWỌLERẸ ỌPẸ́YẸMÍ APÁ KAN IṢẸ́ ÀṢEKÁGBÁ FÚN Ẹ̀KỌ́ ÀKÀGBOYÈ NÍNÚ ÌMỌ̀ ÌPÌLẸ̀ Ẹ̀DÁ Bii Eè NÍNÚ ÈDÈ YORÙBÁ NÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ YUNIFÁSÍTÌ ÌLỌRIN ÌLỌRIN NÀÌJÍRÍÀ OṢÙ IGBE ỌDÚN ÌFỌWỌ́SÍ Iṣẹ́ àkànṣe yìí ni a ti kà tí a sì rí i pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè àti Èdè Nàìjíríà Yunifásítì Ìlọrin Ìlọrin ALÀGBÀ LAYỌ̀ ÒGÚNLỌLÁ ỌJỌ́ ALÁBÒÓJÚTÓ OLÙYẸ̀WÒ ÌTA ỌJỌ́ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N ỌJỌ́ OLÓRÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁ ÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ÌFISỌRÍ Mo fi iṣẹ́ àṣekágbá yìí sọrí Ọlọ́run Olódùmarè àti àwọn òbí mi Onímọ̀ Ẹ̀rọ Akínwọlerẹ̀ àti aya ÌDÚPẸ́ Ọpẹ́ mi àkọ́kọ́ lọ sọ́dọ̀ Olódùmarè ọba arínúróde olùmọ̀ràn ọkàn Ọba àjọkẹ́ ayé Àṣàkẹ́ ọ̀run tó mú kí ó ṣe é ṣe fún mi láti bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ mi láyọ̀ àti láti parí láyọ̀ Ìbà fún ọ atófaratì bí òkè Bákan náà mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí tí ó ṣe atukọ̀ mi wá sáyé Onímọ̀ Ẹ̀rọ Akínwọlere àti aya Akínwọlere fún ìnáwó nára yín àti akitiyan yín gẹ́gẹ́ bí òbí àdúrà mi ni pé ẹ kò ní ṣe é lásán Mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ alábòjútó iṣẹ́ yìí Alàgbà Layọ̀ Ògúnlọlá fún iṣẹ́ takuntakun tí ẹ ṣe fún mi ìtọ́sọ́nà àti ìgbani níyànjú yín ní ìgbà gbogbo mo gbàdúrà pé ẹ kò ní sàsetì láyé yín Bákan náà mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀mọ̀wé Oyèwọlé fún ìmọ̀ràn àti akitiyan tí ẹ ṣe fún mi ọba òkè yóò tún ti yín náà ṣe Mo tún fi àsìkò yìí dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi fún ìgbà àti àkókò tí a jọ lò papọ̀ Lágbára Ọlọ́run ibi gíga la ó ti máa gbúròó ara wa o Mi ò gbọdọ̀ gbàgbé láti dúpẹ́ lọ́wọ́ olólùfẹ́ mi Lamide Balógun fún ìfẹ́ àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀ Ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹ̀gbọ́n mi pàtàkì Àwọn bí i Adéjùmọ̀ Dìran Ògúndòkun Ọládòkun Bùkọ́lá àti àwọn mìíràn tí ń kò le dárúkọ wọn ẹ ṣé fún ìmọ̀ràn àti àdúrà yín ní gbogbo ìgbà bí Ọlọ́run ti wà ẹ kò ní mọ ìyà láyé yín Ní ìparí mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìyá mi Tèmiladé Táíwò Kẹ́hìndé Bọ́sẹ̀ àti Olúmúyíwá fún ìfọwọ́ṣowọ́pọ̀ yín àdúrà mi ni pé ikú kò ní pa wá fún àwọn òbí wa Ẹ ṣeun ÀṢAMỌ̀ Èròǹgbà iṣẹ́ àkànṣe yìí ni láti fi tíọ́rì àṣà ìbílẹ̀ ṣe ìtúpalẹ̀ ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà tí Olú Owólabí kọ Ọ̀kan lára ìwé eréonítàn Yorùbá ni Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú bí aṣọ alágẹmọ ni ìwé eréonítàn Yorùbá tó wà tí iṣẹ́ ti wà lórí wọn ṣùgbọ́n kò tí ì sí iṣẹ́ kankan lórí ìwé eréonítàn yìí Iṣẹ́ àkànṣe yìí jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ lórí ìwé náà èyí ló fà á tí a fi yan iṣẹ́ yìí láàyò Ohun tí ó fa àkànṣe iṣẹ́ yìí ni láti fún wa ní àǹfààní láti mọ àwọn àdìtú tí òǹkọ̀wé dì sínú iṣẹ́ rẹ̀ Yàtọ̀ sí èyí ṣíṣe iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò fún òǹkọ̀wé ní ìwúrí láti gbé iṣẹ́ mìíràn tó dára ju èyí jáde yóò sì sọ òǹkọ̀wé di ìlúmọ̀ọká Òǹkọ̀wé kì í sàdédé gbé iṣẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ láì ni ohun tí ó fẹ́ fi han òǹkàwé tàbí àwùjọ nínú iṣẹ́ rẹ̀ Ọ̀kẹ́ àìmọye ni àṣà tó súyọ nínú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà tí òǹkọ̀wé fẹ́ kí a mọ̀ Àti wí pé gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé òǹkọ̀wé bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn àṣà kan nínú ìwé náà Àṣà ó sí máa ń mú ìdàgbàsókè bá àwùjọ ni Ọ̀nà kan gbòógì láti jẹ́ kí a lè tí iṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò iṣẹ́ àkànṣe yìí ni ṣíṣe àmúlò tíọ́rì ìfojúàṣàìbílẹ̀woiṣẹ́ lítíréṣọ̀ èyí ni yóò sì fún wa ní àǹfààní láti lè fa kòmóòkun iṣẹ́ yìí yọ Nítorí náà tíọ́rì tí ó dá lórí àṣà ìbílẹ̀ ni abẹfẹ́lẹ́ tí a ó fi la ìfun àti ẹ̀dọ̀ iṣẹ́ àkànṣe yìí ÀTẸ ÀKÓÓNÚ Àkọlé i Ìfọwọ́sí Ìfisọrí Ìdúpẹ́ Àṣamọ̀ Ìtọ̀ka olóríjorí ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Ìfáàrà Èrèdí iṣẹ́ ìwádìí Ibi tí ìwádìí gbòròò dé Ọgbọ́n ìwádìí Àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí yìí Ètò ìwádìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN Ìfáàrà Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá Eréoníṣe Yorùbá Ìbẹ̀rẹ̀ àti Ìdìde eréonítàn Tíọ́rì Ìṣàmúlò Tíọ́rì ÌfojúÀṣàÌbílẹ̀woIṣẹ́Lítíréṣọ̀ ORÍ KẸ́TA ÀGBÉYẸ̀WÒ ÌWÉ ERÉONÍTÀN ÀGBÀ TÍ Ń YỌ́LẸ̀ DÀ Ìfáàrà Ìtàn ìgbésí ayé òǹkọ̀wé Ìtàn inú ìwé náà ní ṣókí Ibùdó ìtàn Àhunpọ̀ ìtàn Ọgbọ́n ìsọ̀tàn Àfihàn àwọn ẹ̀dá ìtàn Ìlòèdè ORÍ KẸ́RIN TÍỌ́RÌ ÌFOJÚÀṢÀÌBÍLẸ̀WOIṢẸ́LÍTÍRÉṢỌ̀ Ìfáàrà Tíọ́rì ìfojúàṣàìbílẹ̀woiṣẹ́lítíréṣọ̀ Àṣà ìkóbìnrinjọ Àṣà ìbọ̀wọ̀ fágbà Àṣà ifá dídá Àṣà ayò títa Àṣà ogún pínpín Àṣà ìwọṣọ Àṣà àlejò ṣíṣe Àṣà ìkíni ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ Ìfáàrà Ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí yìí Àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí Ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú Ìkádìí Àkójọ orúkọ ìwé ORÍ KÌÍNÍ ÌFÁÀRÀ Lítíréṣọ̀ kì í ṣe ohun tuntun láwùjọ Yorùbá ó tí wà ọjọ́ ti pẹ́ A le sọ pé àbàtà Yorùbá ti lómi tẹ̀lé kí òjò àwọn Òyìnbó aláwọ̀ funfun tó rọ̀ wa Yorùbá kì í kọ lítíréṣọ̀ wọn sílẹ̀ tẹ̀lé agbárí tàbí ọpọlọ ní ó wà bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn ẹ̀yà Yorùbá ní lítíréṣọ̀ tiwọn tí eré oníṣe sí jẹ́ ọ̀kan lára rẹ̀ ṣùgbọ́n kò sí ní àkọsílẹ̀ Nígbà tí àwọn Òyìnbó de ní àsìkò ìmúnisìn lítíréṣọ̀ di kíkọ́ sílẹ̀ Lítíréṣọ̀ kì í ṣe ohun akùgùùru ṣe iṣẹ́ tí àkóónú rẹ̀ gbòòrò ni iṣẹ́ tí ó gba ìrònújinlẹ̀ àti laakaye ni Ní ọ̀pọ̀ ìgbà lítíréṣọ̀ máa ń fi àwùjọ tàbí ìgbésí ayé òǹkọ̀wé kan hàn èyí kò sí yọ ẹ̀yà Yorùbá sílẹ̀ Yorùbá ka àṣà sí ohun tó ṣe pàtàkì láwùjọ Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tí o wa ni ayé ni o ni àṣà tirẹ̀ Ìdí nìyí tí a fi máa ń sọ wí pé tiwa ni àṣà tiwa ni ìṣẹ̀ṣe Àwa la ni àṣà inú àṣà ni a bí wa sí ó tọ́ ó sí yẹ kí a gbé àṣà wa lárugẹ Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ pé ojúlówó ọmọ Yorùbá ni olú owólabí ilẹ̀ Yorùbá ní o dagba sí ni ó sí tí rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí rẹ̀ èyí tí o ṣe àfihàn nínú ìwé eré onítàn rẹ̀ Àfojúsùn wa ní láti fi tíọ́rì àṣà ìbílẹ̀ wo ìwé eré onítàn Àgbà Tí Ń Yọ Lẹ Da Lílo tíọ́rì àṣà ìbílẹ̀ àti tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì yóò ran wa lọ́wọ́ nítorí nínú àwùjọ kan láti fa àṣà yọ Tíọ́rì náà wa láti daabo bo àṣà àti ìṣẹ̀ṣe àwùjọ kan Wọn gbàgbọ́ pé kò sí àwùjọ tí kó ni àṣà àti iṣẹ́ tirẹ̀ àti pé àṣà àwùjọ kan ni yóò sọ bí ìgbé ayé àwùjọ bẹ́ẹ̀ yóò ṣe rí Èyí kò sí jọ àwùjọ Yorùbá pàápàá sílẹ̀ Onírúurú ní ìwé eréonítàn tí ó wà lórí àtẹ tí ọ̀kẹ́ àimọye ènìyàn sí tí ṣe iṣẹ́ ìwádìí le lórí ṣùgbọ́n kò tí í sí iṣẹ́ kankan lórí ìwé eré onítàn Àgbà Tí Ń Yọ Lẹ Da àti wí pé òǹkọ̀wé tó kọ ìwé kọ kan gbé e jáde fún ìgbádùn nìkan o ni àwọn kókó tí ó fẹ́ fihàn àwọn ènìyàn inú àwùjọ nítorí ohun tí a mọ̀ sí lítíréṣọ̀ jẹ́ dígí tí a fí nwo àwùjọ Ọ̀nà kan gbóògì láti fí mọ ohun tí òǹkọ̀wé ń sọ ní pé kí a ṣe àgbéyẹ̀wò irú ìwé bẹ́ẹ̀ láti jẹ́ kí a ni ìmọ̀ tó dántọ́ lórí kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Yorùbá bọ̀ wọn ní ọ̀rọ̀ tí a ba ń tẹnu mọ́ ju bí kò dun ni a jẹ́ wí pé o ń dun mọ́ ni ni Bẹ́ẹ̀ ni ẹní bèèrè ọ̀rọ̀ ló fẹ́ ìdí rẹ̀ ẹ̀ gbọ́ Bí a ba ń sọ̀rọ̀ ni pa èrèdí iṣẹ́ ìwádìí ohun tí a rí sọ ni ohun tí o ṣe okùnfà irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé ọ̀pọ̀ onímọ̀ lo tí ṣiṣẹ́ lórí ìwé eré onítàn Àgbà Tí Ń Yọ Lẹ Da tí Olú Owolabi kọ ṣùgbọ́n ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní wọn fí wo síbẹ̀ o tún kù ru ìbon ró Ìwádìí ti fihàn wí pé Àgbà Tí Ń Yọ Lẹ Da ti wa lórí àtẹ láti ọdún Èròǹgbà mi ní láti sọ ìwé yìí di ìlúmọ̀ńká àti láti gba ìwé yìí lọ́wọ́ ìparun Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí o ṣokùnfà iṣẹ́ àkànṣe yìí ni láti wo ipa ti ìwé yìí kó ni àwùjọ àti àwọn nǹkan to kù díẹ̀ ka to nínú ìwé òǹkọ̀wé Nípa síse ìtúpalẹ̀ ìwé yìí òǹkọ̀wé yóò ni ìmọ̀ to kun yóò sí rí ìdáhùn sí àwọn nǹkan to farasin nínú ìwé náà Yóò tún jẹ kí a mọ bí òǹkọ̀wé ṣe ṣe àmúlò ọgbọ́n ìsọ̀tàn òwe ẹ̀dá ìtàn àkànlò èdè tó lò bọ́yá ó lọ àwọn nǹkan yìí lọ́nà to dà tàbí lọ́nà aìtọ́ Ní ọ̀nà mìíràn ẹ̀wẹ̀ iṣẹ́ yìí yóò ran òǹkọ̀wé lọ́wọ́ láti mọ àléébù iṣẹ́ rẹ̀ àti láti le ṣe àtúnṣe sí àwọn àléébù náà ti o ba fẹ́ kọ ìwé mìíràn jáde Lára èrèdí iṣẹ́ yìí ni láti wọ bọ́yá òǹkọ̀wé lọ àṣà Yorùbá lọ́nà to dára tàbí o dorí àṣà kodò àti nǹkan tí òǹkọ̀wé fẹ́ kí a mọ̀ nípa dídosí àṣà kodò Yàtọ̀ sí èyí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò ni o tí wáyé lórí ìwé eré onítàn tí olú Owolabí kọ Ọ̀nà láti fi èrò tiwa hàn lórí ìwé eré onítàn Àgbà Tí Ń Yọ Lẹ Da ní o ṣokùnfà iṣẹ́ àkànṣe yìí àti pé àìmọye ọ̀gọ̀rọ́ ènìyàn ní o tí ka ìwé eré onítàn Àgbà Tí Ń Yọ Lẹ Da ni èyí tí o sí jẹ́ wí pé òye ohun tí wọn kà le máa ye wọn tó ṣùgbọ́n láti le jẹ́ kí wọn mọ̀ ohun tí òǹkọ̀wé ń sọ jẹ ohun tí o ṣe pàtàkì sí iṣẹ́ ìwádìí yìí Iṣẹ́ yìí tún wúlò fún àwùjọ yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ àwọn àṣà ilẹ̀ wa àti èyí tí o tí parun láti le ka àwọn àṣà náà jí nípa ṣíṣe iṣẹ́ lámèyítọ́ le lórí iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò gbé àṣà wa lárugẹ IBI TI ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ Kò sí bi ìwádìí ṣe le gbòòrò tó tí kò níní ibi tí yóò dè Gẹ́gẹ́ bí àkọlé iṣẹ́ ìwádìí yìí o ní í ṣe pẹ̀lú àyẹ̀wò fínnìfínní lórí ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ Lẹ Da tí Olú Owólabí kọ Orí márùnún ni iṣẹ́ ìwádìí yìí ìfáàrà ní o sí bẹ̀rẹ̀ orí kọ̀ọ̀kan orí kìíní iṣẹ́ yìí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí Lẹ́yìn ìfáàrà fún orí yìí àwọn nǹkan tí a tún le ṣe alábápàdé níbẹ̀ ni èrèdí iṣẹ́ ìwádìí ibi tí ìwádìí gbòòrò dé ọgbọ́n ìwádìí àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí yìí èyí tí o jẹ́ ìkádìí fún orí kìíní Bẹ́ẹ̀ ni orí kejì títí de orí karùnún Ní ìgbàtí o jẹ́ wí pé Ògún pinpin ní àwùjọ ilé Yorùbá àti kùdìẹkùdìẹ tí o máa ń ṣẹlẹ̀ nínú Ògún pínpín ní ìwé náà dálé Láti le ṣe ìwádìí to jinlẹ̀ a kò ní ṣàì wo Ìbéèrè àti ìdìde eré onítàn A o tún wo èròjà àti àbùdá àṣà tí o súyọ nínú eré onítàn tí òǹkọ̀wé lọ láti fi ìwé ránṣẹ́ sí àwùjọ àti irú àyípadà tí o fẹ kí ìwé náà mú ba àwùjọ ilẹ̀ Yorùbá àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀ Lokotan a o wo àmúyẹ àti àléébù ìwé náà a o sí da ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ ọ̀la ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ Ọgbọ́n ìwádìí tí a ní pọ̀ ṣùgbọ́n díẹ̀ lára wọn ní wọnyìí Lílọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́nàìmọ̀ èyí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ọgbọ́n ìwádìí tí ó wà asewadi yóò lọ sọ́dọ̀ abẹ́nàìmọ̀ láti lọ fọ̀rọ́ wa àwọn abẹ́nàìmọ̀ lẹ́nu wò nítorí àwọn ní o ni ìmọ̀ lórí iṣẹ́ àkànṣe tí o ń ṣe ìwádìí le lórí láti lọ fi ọ̀rọ̀ wa wọn lẹ́nu wò Lílo àtòjọ ìbéèrè ìlànà yìí máa ń fún aṣèwádìí ni àǹfààní láti gbọ́ onírúurú èrò àwọn abẹ́nàìmọ̀ lórí kókó iṣẹ́ kan Ìwòran aṣàkíyèsí èyí ni ọgbọ́n ìwádìí tí o ṣe pé aṣèwádìí le lọ ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀ tàbí fídíò láti ka gbogbo bí ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe ń lọ Òmíràn ni asàkíyèsí akópa èyí ni ọgbọ́n ìwádìí to ṣe pé olùwádìí fún rarẹ̀ yóò kópa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tí o ń ṣe ìwádìí le lórí Irú ọgbọ́n yìí yóò fún fún olùwádìí ni àǹfààní láti rí ìdí kókó nítorí pé o jẹ́ ọ̀kan nínú akópa ìṣẹ̀lẹ̀ náà Lílọ sí yara ìkàwé èyí ni kíka onírúurú ìwé lórí iṣẹ́ aṣèwádìí ń ṣe ìwádìí le lórí Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ wí pé òǹkọ̀wé tó kọ ìwé yìí tí di olóògbé èyí kò fún wa ní àǹfààní láti lọ àwọn ọgbọ́n ìwádìí yìí àyàfi lílọ sí yara ìkàwé A ṣe àgbéyẹ̀wò onírúurú àkọsílẹ̀ tí o wa lórí iṣẹ́ lítíréṣọ̀ A ṣe èyí nípa lílọ sí yara ìkàwé láti wo oríṣiríṣi àkọsílẹ̀ tó sí ní nǹkan ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí Gẹ́gẹ́ bí a tí mọ̀ wí pé ẹnu onikan ní a tí ń gbọ pọ̀nun olú Owólabí tí di olóògbé èyí ni kò fún wa ni àǹfààní láti lọ fí ọ̀rọ̀ wa a lẹ́nu wọ Ẹní tí o ba sí kọ ìwé ní yóò mọ ìdí rẹ̀ tí o fi kọ ìwé àti ohun to fẹ́ fi ìwé rẹ̀ ṣe Nítorí náà ìwọ̀nba àkọsílẹ̀ tí a rí nípa ìgbésí ayé Oludunni Owólabí náà ni a lò ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Ọ̀kanọ̀jọkan ní àǹfààní tí iṣẹ́ ìwádìí yìí le mú ba ẹ̀kọ́ èdè àti àwùjọ Yorùbá lápapọ̀ Lára àwọn àǹfààní náà tí ìwọ̀nyìí Iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò jẹ́ kí a le ni ìmọ̀ to kún nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwùjọ Lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò tọ́ka sí ni kùdìẹkùdìẹ tó wà nínú Ògún pínpín ìwà àìbójúmu tí Dúróyajé hù Gbogbo nǹkan wọnyìí ni iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò ṣe àfihàn rẹ̀ tí a o sí wo ọ̀nà tí a le gbà láti ṣe àtúnṣe irú ìwà bẹ́ẹ̀ láwùjọ wa Ìfojú tíọ́rì àṣà ìbílẹ̀ wo ìwé eré onítàn Àgbà tí ń yọ lẹ da yóò ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní fún òǹkọ̀wé àti òǹkàwé Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ yóò fún òǹkọ̀wé ni àǹfààní láti ṣe àtúnṣe tí o ba yẹ nípa ìtọ́ka sí àmúyẹ àti àléébù ìwé náà Sebí ìpakọ́ onípàkọ́ làá rí ẹní ẹlẹni níì rí tẹni Síwájú sii iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò ran àwọn olùwádìí mìíràn tí wọ́n ba fẹ́ láti ṣe àyẹ̀wò àwọn iṣẹ́ mìíràn tí òǹkọ̀wé yìí tí kọ Iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò wúlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ to ń bọ lẹ́yìn wa nípa ṣíṣe àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ àkànṣe tí o ba jọ irú èyí Nítorí náà irú iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò jẹ́ àtègùn fún akẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ láti fa nǹkan yọ nínú rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ iṣẹ́ náà yóò sí fún òǹkàwé ni ìwúrí láti kọ ìwé tirẹ̀ náà Yàtọ̀ fún èyí ìwádìí yìí yóò jẹ ìwúrí fún àwọn òǹkọ̀wé mìíràn láti máa gbé iṣẹ́ tí o dára ju ti olú Owólabí jáde kí àwọn le ba a ṣe àgbéyẹ̀wò irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ èyí sí le sọ wọn dí olókìkí òǹkọ̀wé láwùjọ Ọ̀pọ̀ ènìyàn ní kò mọ̀ pé lítíréṣọ̀ máa ń ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú àwùjọ ṣùgbọ́n iṣẹ́ yìí yóò jẹ asíniníyè fún àwọn onímọ̀ kan to gba pé iṣẹ́ lítíréṣọ̀ kò ni nǹkan ṣe pẹ̀lú àwùjọ o seẹ́sẹ kí irú àwọn bẹ́ẹ̀ tún èrò wọ́n pa lórí àbá yìí ÈTÒ ÌWÁDÌÍ Èròǹgbà wa nínú àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti fi ojú tíọ́rì àṣà ìbílẹ̀ wo ìwé eré onítàn Àgbà Tí Ń Yọ Lẹ Da Fún àǹfààní ìwé ìwádìí yìí àti kí iṣẹ́ náà le rọrùn A o pínín iṣẹ́ yìí sí ìsọ̀rí márùnún gẹ́gẹ́ bí a ṣe mẹ́nuba sáájú Ni orí kìíní ni a o ti rí i ìfáàrà àti èrèdí iṣẹ́ ìwádìí yìí ibi tí ìwádìí gbòòrò dé ọgbọ́n ìwádìí àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí àti ètò ìwádìí Ní orí kejì ni a ó tí wo aáyan ọ̀mọ̀ràn Bí a tí ṣe ni orí kìíní tí ìfáàrà sáájú bẹ́ẹ̀ ni o rí ni orí kejì pẹ̀lú Àwọn nǹkan mìíràn tí a tún wo ni orí kejì yìí ní àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ lítíréṣọ̀ lórí àṣà ìbílẹ̀ ìbéèrè àti ìdìde eré onítàn eré onítàn Yorùbá oríṣi àṣà Yorùbá nígbà tí tíọ́rì ìṣàmúlò tíọ́rì àṣà ìbílẹ̀ yóò gbẹ̀yìn orí yìí Síwájú sí i àgbéyẹ̀wò ìwé eré onítàn Àgbà Tí Ń Yọ Lẹ Da ní orí kẹ́ta dálé Ni orí yìí a o kókó ṣe ìfáàrà lẹ́yìn náà a o wo ìtàn ìgbésí ayé òǹkọ̀wé àhunpọ̀ ìtàn náà ni ṣókí ibùdó ìtàn ọgbọ́n ìsọ̀tàn àfihàn àwọn ẹ̀dá ìtàn àti ìlò èdè inú ìwé náà yóò gbẹ̀yìn orí yìí Bákan náà ni orí kẹ́rin a o fi ojú tíọ́rì àṣà ìbílẹ̀ wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀ yìí àti bí a o ṣe fi tíọ́rì náà ṣe ìtúpalẹ̀ ìwé eré onítàn Àgbà Tí Ń Yọ Lẹ Da Orí karùnún ni yóò jẹ àgbálọgbábọ̀ fún iṣẹ́ ìwádìí yìí nítorí pé bí ọkọ̀ ba ròkun rọ̀ṣà a fèbúté félèbúté ni Ìfáàrà ni a o kókó sí sí orí yìí lẹ́yìn rẹ̀ ni a o ṣe ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú Nígbà tí ìkádìí yóò sí kásẹ̀ ohun gbogbo nílẹ̀ lórí iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN ÌFÁÀRÀ Kò sí ẹ̀yà kan káàkiri àgbàlaye tí kò ni àṣà àti iṣẹ́ tirẹ̀ Àṣà wonyìí lọ jẹ agbodegba fún ìgbé ayé ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan èyí kò sí yọ ẹ̀yà Yorùbá sílẹ̀ Ní abala yìí ohun tí a fẹ́ gbé yẹ̀wò ni iṣẹ́ tí àwọn ènìyàn tí ṣe lórí àṣà pàápàá jùlọ àṣà Yorùbá Bákan náà a o wo àkọsílẹ̀ tí o tí wa lórí ipa tí àṣà àwùjọ kan kó lórí lítíréṣọ̀ àwùjọ bẹ́ẹ̀ pàápàá jùlọ lítíréṣọ̀ alákọsílẹ̀ Bákan náà a ó wo bóyá a rí àkọsílẹ̀ kankan lórí òǹkọ̀wé Yorùbá tó fi àṣà Yorùbá ṣe ìpìlẹ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀ Ní ìparí orí yìí a ó ṣe àgbéyẹ̀wò tíọ́rì Ajemọ Àṣà Ìbílẹ̀ ohun tó wí àti ìbámu tàbí àíbamu rẹ̀ pẹ̀lú orí ọ̀rọ̀ tí iṣẹ́ yìí dálé ÀṢÀ ÌBÍLẸ̀ YORÙBÁ Yorùbá bọ̀ wọn ní bí a fojú ànà wò òkú ẹbọra a bọ̀ ni lásọ́ ojú ìgbà àtijọ́ kò ṣe é wo àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá mọ́ nítorí ìdàgbàsókè ńlá tó dé ba a Ọ̀kanòjọ̀kan àwọn onímọ̀ lọ tí fún àṣà ni oríkì Lára wọn ní Ọlájubù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ìwé atúmọ̀ èdè túmọ̀ Ìyẹn àṣà gẹ́gẹ́ bí èrò iṣẹ́ ọgbọ́n ìmọ̀ọ́nse iṣẹ́ ọ̀nà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ àwọn ènìyàn kan pàtó ni àsìkò kan pàtó O tún pé é ní ìlàjú Ọlájubù náà kì í àṣà báyìí Àṣà ni àwọn ìlànà àti ètò tó tí di bárakú fún ẹ̀yà kan Àwọn ètò àti ìlànà wonyìí lè jẹ́ tí ẹ̀sìn iṣẹ́ òṣèlú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n yìí tí sọ gbogbo àwọn ètò àti ìlànà wọ̀nyìí gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí àwùjọ gbọdọ̀ tẹ́wọ́ gba tí wọn yóò sí máa tẹ̀lé lóòrekóòre Lóòótó ni pé irú àwọn ìlànà àti ètò wọ̀nyìí kì í sí ni àkọsílẹ̀ síbẹ̀ kì í sí wàhálà láti pa àwọn òfin náà mọ́ Àṣà jẹ́ ohun tí o fẹjú ganan Tí a ba wo ohun tí àwọn onímọ̀ nípa ẹ̀yà èdè sọ pàápàá ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìwé rẹ̀ tí ó pé ni tí o gbé jáde ni ó ṣàlàyé pé Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé Ohun tí o gbòòrò púpọ̀ ni àṣà jẹ́ Àkóónú rẹ̀ sí jẹ mo ẹ̀kọ́ìwà ìmọ̀ ìgbàgbọ́ òfin ọ̀nà ìgbà ṣe nǹkan àti àwọn nǹkan lọ tí èdè èèyàn kọ́ gẹ́gẹ́ bí ara àwùjọ bẹ́ẹ̀ Tí a ba wo oríkì tí yìí fún àṣà a ó rí i pé inú àṣà ganan ni ìṣe wa Nínú àṣà a o sí èdè oúnjẹ ètò ẹbí àti ìdílé ẹ̀sìn oríṣiríṣi orin ètò ìsìnkú ìjọ ọ̀nà tí a ń gba ni ìmọ̀sílara oríṣiríṣi iṣẹ́ ìsẹ̀ǹbáye àti àwọn nǹkan mìíràn Ẹlòmíràn to tún sọ̀rọ̀ lórí àṣà ni Ayọdélé o kì í àṣà báyìí Àṣà jẹ ohun tí o jẹmọ́ ìrírí ìhùwàsí ìgbé ayé ìgbàgbọ́ àti ẹ̀sìn ẹ̀yà kan Àwọn ohun tí ó sò mọ́ ẹ̀yà kan wọ̀nyìí á wá di ohun tí wọn ń ṣe ni gbogbo ìgbà fún ìdí èyí àwọn bẹ́ẹ̀ a wa di àṣà Ìgbà tí gbogbo àwọn nǹkan tí a mọ̀ ẹ̀yà kan mọ́ tí jẹ ohun tí wọn ń ṣe ni gbogbo ìgbà èyí yóò wá di ohun tí wọn tí ọ̀wọ̀ wọ̀ Nínú ìwé atúmọ̀ èdè Àṣà jẹ́ ọ̀nà bí ìsọ̀rí àwọn ènìyàn kan ṣe ń hu ìwà Àwọn ènìyàn wọ́nyìí le kéré wọ́n sí le pọ̀ Àwọn ìwà to di barakú lára wọ́n yìí sí nípa púpọ̀ lórí iṣẹ́ ìṣe àti èdè wọn Nínú èrò tí Òjó Àṣà ni àbùdá àdámọ̀ àwọn ìsọ̀rí àwọn ènìyàn kan tó hàn tó sí lapa nínú èrò ọ̀rọ̀ àkọsílẹ̀ ìtàn ìrònú iṣẹ́ ẹ̀sìn ìrìn ìwọṣọ àti àwọn nǹkan mìíràn tí ó rọ̀ mọ́ ibúgbé àti agbègbè tí orí da wọn sí Ládélé fi ojú kí o gbòòrò wo ohun tí a bá pè ni àṣà ó ní Kò sí ohun tí Yorùbá le rò tàbí ṣe tí kò dìrọ̀ mọ́ àṣà bí ènìyàn tọ̀ tàbí yàgbé ara àṣà wa ni bí ó ń sun bí o ń jẹun ara àṣà Yorùbá ni bí o ń sọ̀rọ̀ bí o ń mójú ara àṣà Yorùbá ni kò sí èrò tàbí iṣẹ́ tí kò ba àṣà lọ láàrín àwọn Yorùbá Abímbọ́lá Bíòbákú ; Obawaya náà fún àṣà ni oríkì Nínú akitiyan àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n wọ̀nyìí a rí kedere pé ìṣẹ̀ṣe gbòòrò púpọ̀ àti pé ohun kárìayé ní Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tí o wa ní ayé ní o ní àṣà àti ìṣẹ̀ṣe tirẹ̀ Àṣà ní ìhùwàsí àwọn ènìyàn kan èyí tí o fi wọn hàn yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀yà ènìyàn mìíràn Àṣà àwùjọ kan ni ẹ̀sìn àwùjọ náà Láìsí àṣà àwùjọ kò le dun A máa ń tójú àṣà ní bí ohun ọ̀gbín kí o máa ba a kú Ẹlòmíràn tí o tún sọ̀rọ̀ nípa àṣà ní Olùdarí àgbà àjò ìgbà kan rí Ó fu èrò rẹ̀ hàn lórí bí àṣà ṣe ṣe pàtàkì tó; ó ní Ohun tí èyí túmọ̀ sí ní pé Àṣà ni àbájáde ìṣe àwùjọ kan fún ìgbà pípẹ́ Àṣà yìí náà ni ó máa ń jẹ kí ìṣe àwùjọ tẹ̀síwájú yálà nípa ohun èlò tàbí iṣẹ́ ọpọlọ nǹkan tí o máa ń mọ òye àwọn ẹgbẹ́ tí o tún ń ṣe àfihàn ọ̀nà tí wọn ṣe rí àgbáyé tí o sí tún ni ohun ọ̀gbín tí àwùjọ kan lè pèsè Gẹ́gẹ́ bí a tí mọ̀ wí pé àwùjọ kọ̀ọ̀kan lọ ní àṣà tirẹ̀ àṣà àwùjọ kan sí yàtọ̀ sí tí òmíràn Ìdálùú ní ìṣèlú ohun tí o jẹ́ ni agbègbè kan le ṣàì jẹ́ àṣà ni ibòmìíràn kò sí àṣà tàbí ìṣẹ̀ṣe tó o dúró sigidi bí omi adágún Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ bẹ́ẹ̀ ni àṣà ń dàgbà sí Gbogbo ohun tí a ń pè ni àṣà lọ ní ìpìlẹ̀ orírun àti ibi tí o tí jẹ́ jáde Àṣà kì í ṣe amutọrunwá àdáyésé ni ohun tí o ba sí dún mọ́ ẹ̀yà kan náà ní yóò di àṣà wọn Èrèdí òwe Yorùbá tí o sọ pé báyìí ni a ń ṣe ni ilé wa èèwọ̀ ní níbomíràn Onímọ̀ mìíràn tó fún àṣà ni oríkì ni Ògúnṣínà o sọ pé Bí a ba ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀ṣe Yorùbá a ń sọ̀rọ̀ nípa bí Yorùbá tí rí bí Yorùbá ti jẹ́ bí Yorùbá ti i ṣe láti àtèkọ́ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ pèpẹ̀ A ń sọ nípa orírun Yorùbá a ń sọ nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti èrò Yorùbá ọgbọ́n àmúṣe Yorùbá ìrònú Yorùbá ìrìnsí ìhùwàsí ìrírí ìmọ̀sí èdè ìjìnlẹ̀ Yorùbá gbogbo ohun tó mú Yorùbá jẹ́ Yorùbá àti ohun gbogbo lápapọ̀ tí a fi mọ Yorùbá ni Yorùbá sọ lédè Gẹ̀ẹ́sì pé Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé Ohun tí o gbòòrò púpọ̀ ni àṣà jẹ́ Àkóónú rẹ̀ sí jẹ́ mó ìmọ̀ ìgbàgbọ́ iṣẹ́ ọ̀nà òfin ìsírí ọ̀nà ìgbà ṣe nǹkan àti àwọn nǹkan bí iṣẹ́ tí ẹ̀dá èèyàn kọ́ gẹ́gẹ́ bí ara àwùjọ bẹ́ẹ̀ Nínú kí àṣà báyìí Ohun tó ń sọ léréfé ní pé àṣà jẹ́ ohun ń ẹ̀dá dà àbájáde ìrírí ẹ̀dá to wa létò títí di àsìkò yìí lára ohun tó pé lásà ni gbogbo ohun tí ẹ̀dá ṣe bí ìrìn iṣẹ́ ohun èlò ìjá ìbùgbé àti àwọn ohun tó ṣe àfihàn wọn nínú ìwà àti ìṣe rẹ̀ èrò ìdájọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ní tí Ale àti Ògúnlọlá àṣà jẹ́ ìwà àti ìṣẹ̀ṣe àwọn ènìyàn kan èyí kì í ṣe ìwà ẹnìkan ṣoṣo bí kò ṣe ìwà àjùmọ̀hù àwọn aláṣà náà Ìwà àjùmọ̀hù yìí lè jẹ́ bí wọn sí ń wọ aṣọ ìṣe wọn oúnjẹ wọn ẹ̀sìn wọn ìwà wọn ìsìnkú àti òkú ṣíṣe èdè tí wọn ń sọ ìgbéyàwó ìsọmọlóníkọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Bákan náà àti wọn gbà pé àṣà ni ọ̀nà tí a le tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí ìlànà ìgbéayé àwọn ènìyàn kan nípa lìlò sínú ìhùwàsí ni ọ̀nà pàtàkì tó mú èrò iṣẹ́ àti iṣẹ́ọ̀nà irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ Ojú tí Ilésanmí fí wo àṣà tún gbòòrò ju ti àwọn aṣáájú rẹ̀ lọ ó ní Àṣà ni ohun gbogbo tó jẹ́ àbùdá ẹ̀yà asùwàdà ènìyàn kan àní gbogbo ohun tí a mọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà ènìyàn ní àdúgbò kan tàbí ni orílẹ̀ èdè kan Oríṣìíríṣìí àṣà ló wà gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nuba sáájú Àwọn òǹkọ̀wé àti oníṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ gbogbo á sì máa fi èyí hàn nínú iṣẹ́ wọn láti ìgbà dé ìgbà ìbá a ṣe nínú ewì ìtàn àròsọ tàbí eréoníṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà tí Olú Owólabí kọ A ó tún tọ́ka sí èyí níwájú ERÉ ONÍṢE YORÙBÁ Kò rọrùn láti fún eréoníṣe ní oríkì kan pàtó Ìdí ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àbá ni àwọn oníṣẹ́ lámèyítọ́ ti dá lórí ohun tí a lè pè ní oríkì eréoníṣe Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ṣàpèjúwe nínú wí pé eréoníṣe ni àkójọpọ̀ eré tí a ṣe fún àwọn òǹwòran Adédèjì pe eréoníṣe ní Ìsínjẹ tí a ṣẹ̀dá tí ó ní àsepọ̀ pẹ̀lú àṣà ẹ̀sìn àti èdè àwọn kan Yàtọ̀ fún eréoníṣe a tún lè rí àwọn eré tí ó ní àbùdá fífí àṣà ẹ̀sìn àti èdè hàn tí kò sì jẹ́ eréoníṣe Bí àpẹẹrẹ eré ìbílẹ̀ àti orò ilé Ọ̀gínní ṣe àlàyé wí pé eréoníṣe ni ìtàn tí a kọ sílẹ̀ fún eré ṣíṣe Àwọn òṣèré máa ń pọ̀ ó dàbí ìgbà tí àwọn ènìyàn bá ń ṣe àsepọ̀ tàbí wọ́n bá ń fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ Eréoníṣe jẹ́ ìsínjẹ iṣẹ́ kan tàbí ìsínjẹ tí ènìyàn kan ó sì lè jẹ́ ti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí a gbé kalẹ̀ láti fi dá àwọn òǹwòran lárayá ki eréoníṣe báyìí Eréoníṣe ni eré tí a kọ sílẹ̀ láti orí ìtàgé tàbí lórí rédíò tàbí ní orí tẹlifísàn Ohun tí ìwé atúmọ̀ èdè yìí ń fúnka mọ́ ni wí pé eréoníṣe gbọdọ̀ jẹ́ kíkọ sílẹ̀ bí ó ṣe wà nínú àṣà aláwọ̀ funfun sọ wí pé eréoníṣe jẹ mọ́ eré àbáláyé tí a fi ń jọ́sìn Ó tún pè é ní ọ̀nà ìsàlàyé ara ẹni tí ó sì tún pè é ní ọ̀nà ìdánílarayá Nípa wí pé eréoníṣe jẹ mọ́ ẹ̀sìn àbáláyé ìwé atúmọ̀ èdè Yagbó Yáàjù ṣe àlàyé wí pé káàkiri àgbáyé ni àwọn ènìyàn ti mú eréoníṣe lò nínú ẹ̀sìn àti ọdún ìbílẹ̀ wọn Ìwé atúmọ̀ èdè Yagbó Yáàjù yìí run wo eréoníṣe gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ ìdánílarayá Ìdánílarayá ló ṣe pàtàkì jùlọ nínú ohun tí a ń lo eréoníṣe fún lóde òní Ṣùgbọ́n nínú àṣà tiwa a kò lè kóyán ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àti ìkọ́nilédè kéré Oríṣìí EréOníṣe Àwọn oríṣìí eréoníṣẹ́ tí ó wà nìwọ̀nyí Eréoníṣe Ládojúdé Eréoníṣe amẹ́rìnínwá Eréoníṣe ẹkúndẹ̀rín Eréoníṣe Ládojúdé pé eré ládojúdé ní ìsínjẹ iṣẹ́ tí ó lágbára tí ó sì le koko tí ó péye tí ó jẹ́ bàbàrà Èdè tó lóòrìn ni a fi ń gbé irú iṣẹ́ tí ó jinlẹ̀ tí ó sì ní ìwọ́hùn àti orin ní a papọ̀ kí òǹkàwé lè ní ìmọ̀lára kí orí rẹ̀ sì wú jáde Àbùdá Eré Ládojúdé Ìsubú olú ẹ̀dá ìtàn ládojúdé tí ó jẹ́ ènìyàn pàtàkì láti ipò gíga tí yóò sí wá di ẹni ilẹ̀ẹ́lẹ̀ Irúfẹ́ ẹ̀dá eréoníṣe ládojúdé gbọdọ̀ ní àléébù ìwà kan tí tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì pè ní Oríṣìíríṣìí aburú lè ṣẹlẹ̀ Ìgbẹ̀san lè wáyé Àwàdà láti tu òǹkàwé tàbí òǹwòran lára lè wáyé A máa ń rí ọwọ́ àwọn tí wọ́n lágbára ju ẹ̀dá lásán lọ Ní òpin eré ara òǹwòran tàbí òǹkàwé yóò balẹ̀ nígbà tí ìbẹ̀rù bá dópin ìkáàánú àti ìbánikẹ́dùn náà le wáyé Eréoníṣe amẹ́rìnínwá Èyí ni àwọn Gẹ̀ẹ́sì ń pè ní Èdè Gíríkì ni orísun ọ̀rọ̀ yìí ìtumọ̀ rẹ̀ nínú èdè Gíríkì ni ṣíṣe àwàdà àti kíkọrin ìpanilẹ́rìnín ni à ń lo eré amẹ́rìnínwá fún Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀gọ́ a máa wáyé níbẹ̀ Àwọn Àbùdá Eré Amẹ́rìnínwá Ayọ̀ àti ìdùnnú ló máa ń gbẹ̀yìn eré Àwọn kókó pàtàkì tí kò jinlẹ̀ lọ títí ni eré amẹ́rìnínwá máa ń dálé Àwọn mẹ̀kúnnù tí wọn kò ní ìṣòro bàbàrà ni a ń bá pàdé nínú irúfẹ́ eré yìí Àwọn aláwàdà ló máa ń pọ̀ nínú àwọn akópaẹ̀dá ìtàn inú irú eré bẹ́ẹ̀ Àṣìmú àsìbù ìwà a máa ṣẹlẹ̀ èyí tí o wa yí bìrí tí ó wá yọrí sí rere tàbí ìdùnnú Àyípadà ibi tí ó fẹ́ ṣẹlẹ̀ yìí le ní ọwọ́ àwọn ẹ̀dá alágbára nínú tàbí kí ó sì déédé kó olú ẹ̀dá ìtàn yọ ẸKÚNDẸ̀RÍN Èyí ni eré tàbí ìtàn tí ó kọ́kọ́ jẹ́ wí pé aburú tàbí ìbànújẹ́ ni yóò yọrí sí tí ó wá yìí bìrí tí ó wá yọrí sí rere tàbí ìdùnnú Àyípadà ibi tí ó fẹ́ ṣẹlẹ̀ yìí le ní ọwọ́ àwọn ẹ̀dá alágbára nínú tàbí kí orí déédé kó olú ẹ̀dá ìtàn yọ ÀWỌN ÀBÙDÁ ERÉ SẸKÚNDẸ̀RÍN Àwọn ẹ̀dá ìtàn sábàá máa ń jẹ́ àdàpọ̀ àwọn ọlọ́lá àti mẹ̀kúnnù A máa dàbí pé aburú yóò ṣẹlẹ̀ sí olú ẹ̀dá ìtàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n aburú a máa yí dànù ní òpin eré ẹ̀rín yóò sì pẹ̀ẹ́kẹ olú ẹ̀dá ìtàn A sábàá máa dálórí àwọn kókó bí i ìfẹ́ owú Ìjàmbá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ÌBẸ̀RẸ̀ ÀTI ÌDÌDE ERÉONÍTÀN Kí àgbàdo tó dáyé nǹkan kan ni adìẹ ń jẹ́ kí ó tó di pé àwọn Òyìnbó dé ni àwọn Yorùbá ti ní eré tiwọn ṣùgbọ́n kò sí ní àkọsílẹ̀ A lè tọpinpin ìbẹ̀rẹ̀ eréonítàn Yorùbá lọ sí ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àti ni wọ́n kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa eréoníṣe Yorùbá Aláàfin Majọtu lo fi ṣe ẹ̀yẹ fún àwọn Òyìnbó méjèèjì yìí lẹ́yìn tí wọ́n ti lo ọ̀sẹ̀ méjì ni Ọ̀yọ́koro tí a tún ń pè ní Katunga Aláàfin Ọ̀yọ́ ọba Majotu pe àpèjẹ fún wọn Nínú àpèjẹ yìí ni ọ̀kan lára àwọn òṣèré tí ó máa ń dá ọba lárayá láàfin ṣeré fún àwọn Òyìnbó Eréoníṣe máa ń jẹyọ láti inú ìbọ àwọn òrìṣà bí i Ọbàtálá àkókò ijó eégún aláré àti ayẹyẹ mìíràn tí ó jẹ mọ́ ọdún ìbílẹ̀ Eégún tí wà tẹ́lẹ̀ rí ní IléIfẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oríṣi orò ajẹmẹ́sìn ki aláàfin Ṣàngó tó wá sọ ọ́ di ohun tí ó fi ń ṣe ìrántí Ọ̀rànyàn tí ó jẹ́ bàbá rẹ̀ ni òde Ọ̀yọ́ Èyí ni pé Ṣàngó ni ó dá orò ìṣekùù sílẹ̀ Òkú Ọ̀rànyàn sì ni ó kọ́kọ́ fi eégún fa Ní ayé Ọ̀finràn ni egúngún sí awo àti apá kan lára ọ̀nà tí a fi ń ṣe ìjọba Ìran Ìgbórí àti ọlọ́ba ni ìran eégún méjì tí ó wá láti Tápà sí Ọ̀yọ́ Ọ̀finràn fi ara wọn jẹ́ oyè wọ́n sì ń ṣe ètò eégún fún un Alapinni tí ó wá láti ìran Ìgbórí ni ó fi jẹ́ olórí àwọn eléégún pátápátá Ọlọjẹ́ ẹni tí ó wá láti ìran ọlọ́ba ní ó sì fi jẹ oyè olórí awo Ológbo tí ó wá láti ìran ọlọ́ba ni ó sì fi jẹ oyè ẹni tí o ń ṣe kòkárí àkóso ìṣeré ní àkókò orò ṣíṣe Ní ayé ọba Abiipa ni eégún aláré tó dìde Abiipa fẹ́ kó oyè kúrò ní Ìgbòho padà si Ọ̀yọ́ Àjàká Ṣùgbọ́n àwọn Ọ̀yọ́mèsì kò fẹ́ bẹ́ẹ̀ Alapinni bá àwọn Ọ̀yọ́mèsì yòókù lẹ̀dí àpò pọ̀ wọ́n sì rán àwọn abirùn mẹ́ta lọ sí Ọ̀yọ́ Àjàká láti lọ máa dẹ́rùba àwọn tí aláàfin rán lọ ṣe ètùtù Ṣùgbọ́n ológbìnín tí ó jẹ́ ológbò ọba rí àṣírí ó sì ṣe òfófó fún aláàfin Aláàfin ránṣẹ́ kí wọ́n lọ kó àwọn abirùn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ó sì mú kí wọ́n ṣeré fún àwọn Ọ̀yọ́mèsì Ní ìgbà tí eréoníṣe kúrò ní ti eégún aláré ni ó wá bọ́ sí tí ìlànà Ògúnǹdé Lẹ́yìn tí àṣà òde òní bẹ̀rẹ̀ ni eréoníṣe onílànà Ògúnǹdé tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tó o bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu Tíátà mùtúmùwà Èyí tọ́ka sí tíátà tí ó wà fún gbogbogbòò Àbùdá pàtàkì gbígbé eré káàkiri láti ibìkan dé ibìkejì kì í ṣe ti eréoníṣe onílànà Ògúnǹdé nìkan Ní ìgbà tí Ògúnǹdé gbé eréonítàn lọ sí ilẹ̀ ní ọdún kò rẹ́ni wò ó nítorí pé irú eréonítàn bẹ́ẹ̀ kò gbajúmọ̀ Ní ọdún tí ó tún gbé eré lọ sí ilẹ̀ Àgànyìn eré tí ó jẹ mọ́ ti ìlànà kọ́ńsáàtì báyìí ó ń gbé lọ Ní àkókò yìí náà ni àwàdà ṣíṣe nínú eréonítàn kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí i farahàn kedere nínú eréoníṣe onílànà Ògúnǹdé Lẹ́yìn òmìnira ìdàgbàsókè tuntun súyọ nínú eré onílànà Ògúnǹdé Ní àkókò yìí Ògúnǹdé bẹ̀rẹ̀ sí wá àkọlé Yorùbá fún àwọn eréonítàn rẹ̀ Yorùbá Ronú tí ó jẹ́ eré tuntun ní àkókò yìí ni ó fi bẹ̀rẹ̀ ìlànà tuntun náà ÌDÀGBÀSÓKÈ ERÉONÍṢE Ìdàgbàsókè yìí ní ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sìn Kírísítì àti àwọn Òyìnbó pẹ̀lú àwọn ọmọ Yorùbá tí ojú wọn ti là Ní àárín Sẹ́ńtúrì kọ́kàndínlógún ni onírúurú àwọn ìjọ Kírísítì ti Ìwọ̀ Gúsù ilẹ̀ wa tí wọ́n sì tẹ̀dó sí ìlú Èkó àti Abẹ́òkúta Títan ìhìnrere ká nìkan kọ́ ló jẹ àwọn ẹlẹ́sìn yìí lógún wọ́n fẹ́ la àwọn Yorùbá náà lójú Lára ẹgbẹ́ tí wọ́n kọ́kọ́ dá sílẹ̀ ni ní ọdún Èròǹgbà wọn ní í ṣe pẹ̀lú ìdàgbàsókè ọ̀rọ̀ ọ̀làjú ètò ìṣèlú ètò ọrọ̀ajé àti ẹ̀mí ìsìn Ní ni ẹgbẹ́ kan tún bẹ̀rẹ̀ eré ní Èkó Eré yìí jẹ mọ́ fífi orin sọ̀tàn inú Bíbélì Nínú eré wọ́n ṣe ni olùdarí tàbí eré aforinsọ̀tàn yìí ÌPÍN SÍ ÌSỌ̀RÍ ERÉONÍTÀN Ọ̀nà méjì pàtó ni a ti gbìyànjú láti ṣe ìpínsísọ̀rí eréoníṣe Yorùbá Ìṣọ̀lá lo ìgbìyanjú àkọ́kọ́ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì EEM Ee MA nínú àkóso Ọ̀mọ̀wé Ògúndèjì ní ọdún Nínú ìpínsísọ̀rí tí Akínwùmí Ìṣọ̀lá ṣe ó pín eréoníṣe sí ìsọ̀rí mẹ́ta Adálórí ìtàn gidi Adálórí ìtàn fèyíkọ́gbọ́n Adálórí ìfẹ̀hónúhàn ADÁLÓRÍ ÌTÀN GIDI Àwọn eré tí Ìṣọ̀lá pín sí ìsọ̀rí adálórí ìtàn gidi ni àwọn tí òǹkọeré gbé ka orí ìtàn tí ó ṣẹlẹ̀ rí Ara àwọn àpẹẹrẹ tí a lè tọ́ka sí ni Ìṣọ̀lá Ẹfúnṣetán Aníwúrà Baṣọ̀run Gáà Ògúnníran Ààrẹ Àgò Aríkúyẹrí Owólabí Lísàbí Agbòǹgbò Àkàlà Àwọn yìí jẹ́ ìtàn gidi tí ó ṣẹlẹ̀ ní ìgbésí ayé Yorùbá Kì í ṣe dandan ni kí ó jẹ́ pé gbogbo òdodo pátá tí ó wà nínú ìtàn ni yóò hàn nínú eré Ohun tí òǹkọ̀wé bá gbà pé yóò mú eré dùn tí yóò ran iṣẹ́ tí ó fẹ́ jẹ́ lọ́wọ́ ni yóò lò Ó lè ṣe àfikún ó sì lè yọ kúrò ADÁLÓRÍ ÌTÀN FÈYÍKỌ́GBỌ́N Àwọn eré tí òǹwòran àti òǹkàwé máa ń rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú rẹ̀ ni Ìṣọ̀lá pín sí abẹ́ akọ́nilọ́gbọ́n Àwọn àpẹẹrẹ eré tí a lè pín sábẹ́ ìsọ̀rí yìí ni; Ọlátúnjí Àṣírí Tú Fálétí Nwọ́n Rò pé Wèrè Ni Ó dàbí ẹní pé èrò Ìṣọ̀lá múra di ni wí pé òǹkọ̀wé tí a pín sábẹ́ ìsọ̀rí yìí ni òǹkaeré tàbí òǹwòran lè rí ọgbọ́n kọ́ADÁLÓRÍ ÌFẸ̀HÓNÚHÀN Ìsọ̀rí kẹ́ta tí Ìṣọ̀lá pín eré sí ni afẹ̀hónúhàn Àwọn eré tí ó fi ṣe àpẹẹrẹ ni àwọn eré tí wọ́n ń fi ẹ̀hónú hàn nípa bí àwọn ọlọ́lá àti àwọn agbaniṣíṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba ṣe ń mú mẹ̀kúnnù sìn tí wọ́n di aláìlágbára nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú àti ọrọ̀ajé Àwọn eré tí Ìṣọ̀lá tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ni Òkédìjí Rẹ́rẹ́ Rún àti Ìṣọ̀lá Kò Seégbé TÍỌ́RÌ ÌṢÀMÚLÒ TÍỌ́RÌ ÌFOJÚÀṢÀÌBÍLẸ̀WOIṢẸ́LÍTÍRÉṢỌ̀ Yorùbá bọ̀ wọ́n ni a kì í ṣòṣà lódò kí làbẹlàbẹ má mọ̀ Kò rọrùn láti ṣe lámèyítọ́ tí ó kira lórí iṣẹ́ òǹkọ̀wé lítíréṣọ̀ alátinúdá kan láì ṣe àmúlò tíọ́rì kan tàbí òmíràn Adéyẹmí fi tíọ́rì wé abẹfẹ́lẹ́ ìmọ̀ tí a fi ń la ìfun àti ẹ̀dọ̀ iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ó tún sọ ọ́ síwájú pé nínú ìmọ̀ Sáyẹ́ńsì ni tíọ́rì ti jẹyọ àti pé ìwádìí yòówù tí kò bá gùnlé tíọ́rì kan pàtó kò le gbóúnjẹ fẹ́gbẹ́ kó tún gbàwo bọ̀ Tíọ́rì yìí ni ohun èlò pàtàkì tí ó le mú kí a rí kọjá ohun tí ó wà nínú iṣẹ́ tí òǹkọ̀wé kan kò sì ṣe é ṣe kí a mọ̀ iṣẹ́ tí òǹkọ̀wé ń fi ìwé rẹ̀ rán sí àwùjọ bí a kò bá ṣe àmúlò tíọ́rì láti ṣe àtúpalẹ̀ irú ìwé bẹ́ẹ̀ Èyí ló mú Ọbafẹ́mi sọ nípa tíọ́rì lítíréṣọ̀ báyìí pé Tíọ́rì ni irinṣẹ́ ìmọ̀ nípa ẹwà lítíréṣọ̀ láti jẹ́ kí ìbásepọ̀ ó wà láàárín ìran òǹkọ̀wé ìmọ̀ọ́nṣe rẹ̀ àti ìbánisọ̀rọ̀ tó péye Ohun tí Ọbafẹ́mi ń sọ ni pé ohun èlò ìgbóye ìmọ̀ yọ ni gbogbo ìmọ̀ ọgbọ́n òye ìran àti ìmọ̀ọ́ṣe òǹkọ̀wé kò le di mímọ̀ fún aráyé láìṣí tíọ́rì Adégbìjà R ṣàlàyé pé Tíọ́rì lítíréṣọ̀ máa ń ṣe ààtò lọ́nà àrà onírúurú oríkì àti ìlànà tí a ti gbékalẹ̀ fún ẹ̀kọ́ àti ìgbéléwọ̀n iṣẹ́ lítíréṣọ̀ Onírúurú bí aṣọ alágẹmọ ni tíọ́rì lítíréṣọ̀ tí ó wà Díẹ̀ lára àwọn tó gbajúmọ̀ lágboolé lítíréṣọ̀ ni wọ̀nyí Tíọ́rì ìfojú ààtòwo iṣẹ́ lítíréṣọ̀ Tíọ́rì ìfojú ìhun wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀ Tíọ́rì ìfojú ìtàn ìgbésí ayé òǹkọ̀wé wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀ Tíọ́rì Ìṣègbèfábo Tíọ́rì ìfoju ìmọ̀ ìbára ẹni gbépọ̀ láwùjọ wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀ tàbí Soṣíọ́lọ́jì Tíọ́rì ìfojú Àṣàìbílẹ̀ woiṣẹ́lítíréṣọ̀ Tíọ́rì tí a ó ṣàmúlò nínú iṣẹ́ yìí ni tíọ́rì àṣà ìbílẹ̀ Fanon àti Ngugi wa tí wọ́n jẹ́ agbátẹrù tíọ́rì yìí sọ pé iṣẹ́ tí lítíréṣọ̀ máa ń ṣe ní láti dáàbò bo àṣà àti ìṣẹ̀ṣe àwùjọ kan nítorí náà ohun tí ó gbọdọ̀ jẹ lámèyítọ́ lógún ni ṣíṣe àfihàn irú àwọn àṣà tó súyọ nínú iṣẹ́ ọ̀nà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ Abímbọ́lá sọ pé Kí a tó le rí ìlànà lámèyítọ́ lítíréṣọ̀ tí yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà a níláti jẹ́ kí irú ìlànà bẹ́ẹ̀ bí ó ti wù kí ó jẹ́ ti òde òní tó ó gbọdọ̀ ní ọwọ́ àṣà nínú bí bẹ́ẹ̀ kọ́ òfégè lásán ni iṣẹ́ lámèyítọ́ bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa tíọ́rì Àṣà ìbílẹ̀ àwọn àṣà Yorùbá ni òǹkọ̀wé ń gbìyànjú láti mú wá sí ìrántí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ Nínú iṣẹ́ yìí a ó wo bí àwọn àṣà tí ó súyọ nínú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà ṣe wúlò fún àwùjọ àti bóyá àwọn àṣà náà le fa ìlọsíwájú bá àwùjọ àti bí àṣà náà ṣe wúlò fún àwùjọ Àwọn agbátẹrù tíọ́rì yìí pín àṣà sí ọ̀nà méjì àwọn ìṣọ̀wọ́ kìíní rí àṣà gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò gbọdọ̀ yípadà Àṣà tí kò sayé lóore ni wọ́n sì ń gùnlé irú àkójọpọ̀ àṣà bẹ́ẹ̀ kì í fẹ́ ìjà kì í fẹ́ ìta kí a sáà máa wòran kí a máa bẹ̀rù àgbà kí a bẹ̀rù àwọn ajunilọ bí wọ́n tilẹ̀ ń fọwọ́ ọlá gbá wa lójú Ìṣọ̀wọ́ kejì ni àwọn tó gba àṣà ni ohun atáyéṣe àkójọpọ̀ àṣà tí ó lè tanijí tí ó lè gún àwọn mẹ̀kúnnù ní kẹ́ṣẹ́ inú láti dìde fún ìjàgbara ni wọ́n ń kójọ Irú èyí ni àti ń ṣe lálàyé Àṣà tó ṣe é tẹ̀lé àṣà tó ṣe é fi yangàn lójú àwọn abínú ẹní irú àṣà bẹ́ẹ̀ ló yẹ kí òǹkọ̀wé máa ṣe àwárí àti àfihàn nínú iṣẹ́ ọnà rẹ̀ Ngugi wa sọ pé nípa lílo èdè abínibí fún kíkọ́ lítíréṣọ̀ a ń gbé àṣà lárugẹ ni Nínú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà Olú Owólabí ṣe àfihàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá bí ìbọ̀wọ̀fágbà àṣà ìsìnkú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní èyí tí a sì ń rí ní àwùjọ wa lónìí Ìdí tí a fi ṣe àmúlò tíọ́rì Àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá ni wí pé inú àwùjọ ni àti rí àṣà inú àṣà sì ni a bí wa sí Àwọn ìlànà àti ètò tó ti di bárakú fún ẹ̀yà kan bí ìṣèlú ètò ọrọ̀ajé àṣà ni wọ́n Inú àwùjọ sì ni a ti ń ṣe àmúlò àwọn nǹkan wọ̀nyí Kò dájú pé òǹkọ̀wé Yorùbá kan lè kọ ìwé fún àwùjọ Yorùbá láì fi ti ọ̀rọ̀ àṣà ṣe Ìdí ni pé nínú iṣẹ́ kíkọ́ a gbọdọ̀ rántí pé àṣà àwùjọ ló sábàá máa ń sọ bí ìgbéayé àwùjọ bẹ́ẹ̀ yóò ṣe rí nítorí náà ó ṣe pàtàkì fún òǹkọ̀wé láti ní ìmọ̀ nípa àṣà àwùjọ Èyí yóò fún un ní àǹfààní láti lè ṣe ìdájọ́ bóyá ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ kan bá ìgbéayé àwùjọ bẹ́ẹ̀ mu tàbí kò bá a mu Nínú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà a rí àfihàn àṣà Yorùbá lọ́kànòjọ̀kan a sì rí ìhà tí òǹkọ̀wé kọ sí àwọn ẹ̀dá ìtàn tó lò lòdì sí àṣà àwùjọ nínú ìwé náà gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe fihàn níwájú ORÍ KẸ́TA ÀGBÉYẸ̀WÒ ERÉONÍTÀN ÀGBÀ TÍ Ń YỌ́LẸ̀ DÀ ÌFÁÀRÀ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ìpàkọ́ onípàkọ́ là á rí ẹni ẹlẹ́ni ní í rí tẹni Ní orí yìí ni a ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà láti mọ kùdìẹ̀kudiẹ tó wà níbẹ̀ Èyí ṣe pàtàkì nítorí ó ṣe é ṣe kí òǹkọ̀wé fúnra rẹ̀ má ṣàkíyèsí irú àléébù tí a ń wí yìí A bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtàn ìgbésí ayé òǹkọ̀wé láti mọ bí ìrírí rẹ̀ ṣe tó èyí yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti sọ àsọdátọ́ ọ̀rọ̀ lórí iṣẹ́ rẹ̀ Lẹ́yìn èyí a ó wo ìtàn náà ní ṣókí A ó tún tẹ̀síwàjú láti wo ibùdó ìtàn àhunpọ̀ ìtàn ọgbọ́n ìsọ̀tàn àfihàn àwọn ẹ̀dá ìtàn àti ìlò èdè inú ìwé náà Bákan náà ni a ó wo ipa tí àṣà ìbílẹ̀ kó nínú eréonítàn náà ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ ÒǸKỌ̀WÉ A bí Olú Owólabí ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kìíní ọdún ọmọ bíbí ìlú Ìgbogilà ní Ẹkùn Yewa ní ìpínlẹ̀ Ògùn Owólabí ni orúkọ bàbá rẹ̀ nígbà tí orúkọ ìyá rẹ̀ sì jẹ́ Àṣàbí Owólabí Bàbá rẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́sìn Kírísítì tí ó gbóná Èyí ni ó fún Olú Owólabí ní àǹfààní láti tètè bẹ̀rẹ̀ iléìwé ní ìgbà èwe rẹ̀ Ìdí abájọ èyí ni pé àwọn ọmọ ẹlẹ́sìn Kírísítì ni wọ́n máa ń sábàá gbà sí iléìwé ní àsìkò tí à ń wí yìí Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní iléẹ̀kọ́ ti Ìjọ Elétò tí ó wà ní Ìgbogilà ní ọdún lẹ́yìn ọdún méjì níbẹ̀ ó tún lọ sí ilẹ̀ẹ̀kọ́ ti Ìjọ Onítẹ̀bọmi tí a mọ̀ sí Sàjẹ́ Òkè Sàjẹ́ tí ó wà ní Abẹ́òkúta Ibí ni ó sì ti jáde ìwé mẹ́fà Olú Owólabí kò dúró níbẹ̀ ó tún tẹ̀síwàjú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni Onípò kẹ́ta tí ó wà ní ìlú Ìláròó ní ọdún lẹ́yìn èyí ni ó tún lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Onípò kejì ti Ṣágámù Rẹmọ ní ọdún Ó ṣe àṣeyọrí ní ọdún ní àsìkò tí ó fi wà ní ilé ẹ̀kọ́ yìí òun ni wọ́n fi jẹ oyè aṣáájú fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù Lẹ́nu iṣẹ́ olùkọ́ ni olú Owólabí wà tí ó fi ṣe ìdánwò oníwèé mẹ́wàá ìdánwò oníwèé méjìlá ó ṣe ìdánwò yìí láàárín ọdún sí ọdún Ní ọdún ni ó tún wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga jùlọ Yunifásítì tí ìlú Ìbàdàn láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Ìmọ̀ Àgbáyé Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ọdún pẹ̀lú ayọ̀ ni ó fi padà sí ibi iṣẹ́ olùkọ́ tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí wọ́n sì gbé e lọ sí ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ Olùkọ́ni Onípò kejì tí a mọ̀ sí Ṣágámù ní agbègbè Rẹ́mọ Ní ọdún ó tún gba Yunifásítì kan lọ ní ìlú Òyìnbó èyí tí a mọ̀ sí ó gba oyè lórí ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa iṣẹ́ Olùkọ́ni Ó tún ṣe iṣẹ́ olùkọ́ àgbà ní ilé ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni ní Oǹdó láti ibẹ̀ ni iṣẹ́ ti gbé e lọ sí Ẹ̀gbádò Ìlaròó Níbẹ̀ ni ó ti fẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ọba Ní àsìkò tí ó ṣe iṣẹ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ilẹ̀ ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni Onípò kejì ní ọdún ni ìfẹ́ rẹ̀ sí èdè Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ sí hàn nítorí àkókò yìí ganan ni ó kọ ìwé àkọ́kọ́ rẹ̀ tí ó pe àkọlé rẹ̀ ní Orí Adé Kì í Sùnta Àkókò ìsinmi tí ọwọ́ rẹ̀ sì dilẹ̀ ni ó kọ ìwé yìí olú Owólabí ní ìyàwó Ọlọ́run sì fi àwọn ọmọ ta á lọ́rẹ ÌTÀN INÚ ÌWÉ NÁÀ NÍ ṢÓKÍ Dúrójayé ni olú ẹ̀dá ìtàn inú ìwé náà Baba Kékeré tí ó jẹ́ bàbá Àjàní ti kú Dúrójayé tí ó sì jẹ́ àbúrò bàbá Àjàní ló tọ́ Àjàní dàgbà òun náà ló sì kù fún un gẹ́gẹ́ bí bàbá Dúrójayé ní ìyàwó mẹ́ta Ṣọlábòmí Àkànkẹ́ àti Eebudọla Wọ́n sin òkú Baba Kékeré Nítorí àtijogún Dúrójayé fi èpè ránṣẹ́ sí méjì nínú àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó wà lẹ́hìn odi Ó fi Àjàní tí ó kéré jù nínú àwọn ọmọ náà sọ́dọ̀ Àjàní dàgbà ó gbéyàwó láìpẹ́ iṣẹ́ sì gbé e lọ sí ìdálẹ̀ ó fi ìyàwó rẹ̀ Àríkẹ́ sí ọ̀dọ̀ Dúrójayé ẹni tí ó kù fún un gẹ́gẹ́ bí bàbá ṣùgbọ́n Dúrójayé ń bá Àríkẹ́ ní àjọsepọ̀ ní ìgbà tí Àjàní lọ sí ìdálẹ̀ Ẹni tí a fi sí ipò bàbá tí kò hu ìwà tí ènìyàn lè fi máa bọ̀wọ̀ fún un Ní ìgbẹ̀yìn àṣírí tú sí ọwọ́ Àjàní Dúrójayé sì káàbámọ̀ ohun tí ó ṣe Ní ilé ẹjọ́ adájọ́ ní kí Dúrójayé lọ ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún kan gbáko pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára ní ìgbà tí Dúrójayé gbọ́ èyí ó mú ìgò kékeré kan jáde nínú àpò rẹ̀ ó sì dà á sẹ́nu Dúrójayé kú ní ìgbẹ̀yìn nítorí ìtìjú Ìtìjú pàápàá ti Àríkẹ́ ìyàwó Àjàní tí ń bá bàbá ọkọ rẹ̀ ní àjọsepọ̀ A rí nínú ìwé yìí wí pé àgbà tí a fi sí ipò àgbà tí ó yẹ kí ó ṣe bí Baba fún ni ni ó tún ń hu ìwà burúkú IBÙDÓ ÌTÀN Ibùdó ìtàn ni ibi tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn yìí ti wáyé Nínú ìwé eréonítàn ibùdó ìtàn lè jẹ́ ilé orílẹ̀èdè ìta gbangba Ọ̀nà méjì pàtàkì ni a lè pín ibùdó ìtàn sí abáyému àti àìbáyému Ibùdó ìtàn àìbáyému ni èyí tí a sábàá máa ń bá pàdé nínú àwọn ìwé Fágúnwà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú rẹ̀ máa ń wáyé ní ayé tàbí ọ̀run ìlú àwọn iwin ìlú àwọn òkú abẹ́ omi tàbí nínú òfuurufú gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí nínú àwọn ìwé Fágúnwà márààrún Ibùdó ìtàn abáyému jẹ́ ibùdó tí ìṣẹ̀lẹ̀ ibẹ̀ máa ń jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ojú ayé tàbí èyí tí a tọ́ka sí Àwọn orúkọ ìlú tàbí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàn wọ̀nyí le jẹ́ àwọn èyí tí a mọ̀ láwùjọ Yorùbá Láti ìgbà tí àwọn onímọ̀ ti ṣe lámèyítọ́ ìwé ìtàn àròsọ Fágúnwà ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé òde òní kò ti lo ibùdó ìtàn àìbáyému mọ́ èyí kò sì yọ ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà sílẹ̀ Ní ilé kan ní ìtàn ti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìlú mìíràn tí òǹkọ̀wé tún dárúkọ ni Gánà ní ibi tí àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n Dúrójayé méjì tó kù wà Dúrójayé sọ báyìí ní ìgbà tí wọ́n fẹ́ pín ogún ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Dúrójayé Alàgbà Akíndélé ẹ gbàgbé àwọn tẹ̀hìn odi ẹ sá jẹ́ kí a parí tí àwa tí a wà nílé tán kí a tó máa sọ̀rọ̀ èrò ẹ̀hìn odi Àwọn tí wọ́n ti gbé sí Gánà Wọ́n tilẹ̀ ní góòlù ni èyí ẹ̀gbọ́n ń tà lọ́hùnún wọ́n ni àbúrò ń ta aṣọ oe Òǹkọ̀wé tún dárúkọ Gbáremú ní ìgbà tí Àjàní wa sọ fún Dúrójayé pé iṣẹ́ ti gbé òun lọ sí Gbáremú òǹkọ̀wé ṣe àpèjúwe báyìí Dúrójayé Gbáremú! Gbáremú! Bí ó ti máa ń yá náà nù un? Gbáremú A gbọ́ pé orúkọ ìlú dará njẹ́ ìlú náà kò ti wá jìn jù báyìí Yóò fẹ́ẹ̀ tó ìrìn ẹgbẹ̀ta ibùsọ̀ àbi ẹ ti pé mo wí? oe Ibùdó ìtàn mìíràn ni ilé Àríkẹ́ níbi tí Dúrójayé sùn sí àti ibi tí wọ́n ti jọ mulẹ̀ ìyẹn ilé Àríkẹ́ ÀHUNPỌ̀ ÌTÀN Onírúurú ọ̀nà ni àwọn òǹkọ̀wé eréonítàn òde òní máa ń gbà láti gbé ìtàn wọn kalẹ̀ Òmíràn le mú ìtàn náà láti ìbéèrè lọ sí òpin àwọn mìíràn a bẹ̀rẹ̀ láti àárín tàbí ìparí wá sí ìbẹ̀rẹ̀ Bí ó bá ti wuni là ń ṣe ìmàle ẹni ni ọ̀rọ̀ náà rí Ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà jẹ́ ìtàn tí ó dùn tí ó sì mú ni lára Èyí kò sí ṣe lẹ́yìn onírúurú àtinúdá tí òǹkọ̀wé lò láti hun ìtàn náà pọ̀ Ìtàn inú ìwé náà lọ́ tààrà ó sì já geere Ní idán kìíní ni ẹ̀gbọ́n Dúrójayé ti kú tí wọ́n sì ṣe ìlérí fún Àjàní láti tọ́ ọ dàgbà Ní idán kejì ni wọ́n ti ṣe ayẹyẹ wí pé Àjàní parí ìwé mẹ́wàá ní idán kẹ́ta ni wọ́n ti pín ogún ṣùgbọ́n tí Dúrójayé kọ̀ jálẹ̀ pé kí wọn pín ogún bí òun ṣe ní kí wọ́n pín in Ní idán kẹ́rin ni Dúrójayé ti lọ sí ilé Àríkẹ́ àti ibi tí Èebudọlá ti lá àlá nípa ọkọ rẹ̀ idán karùnún ni Dúrójayé ti bá Àríkẹ́ ní àjọsepọ̀ ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà Ní idán kẹfà ni a ti rí ibi ayò níbi tí òfófó ohun tó ń lọ ní ìlú ti ń ṣẹlẹ̀ àti bí Ọlọ́pàá ṣe fi ẹ̀sùn kan Dúrójayé tí wọ́n fi sọ ọ́ sí ẹ̀wọ̀n ṣùgbọ́n nítorí ìtìjú ó pa ara rẹ̀ ỌGBỌ́N ÌSỌ̀TÀN Ìrírí ni baba ọgbọ́n àròjinlẹ̀ ni baba ìmọ̀ ká sọ̀rọ̀ ká yọ kòómòkun ní í mú ni pegede láwùjọ àwọn òǹkọ̀wé lítíréṣọ̀ alátinúdá Ìtàn inú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà kò déédé dùn bíkòṣe onírúurú ète àti ọgbọ́n àtinúdá tí òǹkọ̀wé fi gbé e kalẹ̀ Lára ọgbọ́n ìsọ̀tàn tí Olú Owólabí lò ni ọgbọ́n ìsọ̀tàn lò ni ọgbọ́n ìsọ̀tàn àlá lílá ọgbọ́n ìsọ̀tàn ìtàn nínú ìtàn A ó ṣàlàyé díẹ̀ nínú wọn ỌGBỌ́N ÌSỌ̀TÀN ÀLÁ LÍLÁ Fágúnwà ni òǹkọ̀wé àkọ́kọ́ tí a lè tọ́ka sí pé ó lo ọgbọ́n ìsọ̀tàn yìí nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ rẹ̀ Ọ̀kanòjọ̀kan àwọn onímọ̀ ló ti sọ̀rọ̀ lórí ipa tí àlá máa ń kó nínú ìtàn àròsọ Lára àwọn onímọ̀ bẹ́ẹ̀ ni a ti rí Bámgbóṣé Ògúnṣínà àti Adéyẹmí Àwọn onímọ̀ wọ̀nyí gbà pé àlá máa ń sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ó sì máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ dàbí òótọ́ Ohun tí àlá ṣe nínú ìwé Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà ni pé ó fi ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa àlá lílá hàn Ìran Yorùbá ní ìgbàgbọ́ tó gbópọn nínú àlá lílá Wọ́n a máa ṣe akitiyan láti wá ìtumọ̀ sí àlá tí wọ́n bá lá Òǹkọ̀wé ṣe àfihàn ọgbọ́n ìsọ̀tàn yìí ní ìgbà tí Èébúdọlà lá àlá nípa ọkọ rẹ̀ Dúrójayé wí pé ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà Ìgbàgbọ́ tí àwọn ìyàwó Dúrójayé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni nínú àlá lílá ló jẹ́ kí wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá awo Èébúdọlà Ẹ ṣeun ǹjẹ́ ẹ ò ní máa rò pé adákúkoosan ni mí báyìí Ìsípayá yìí mà mà ga o oe ỌGBỌ́N ÌSỌ̀TÀN ÌTÀN NÍNÚ ÌTÀN Olú Owólabí tún lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti gbé ìtàn mìíràn wọnú ìtàn rẹ̀ Ẹnu Ṣọlábòmí ló fi ìtàn yìí sí Bí àpẹẹrẹ Ṣọlábòmí sọ ìtàn ìjàpá àti gbogbo ọkùnrin ayé ní ìgbà tí ó sọ báyìí Ṣọlábòmí Ẹ ò rántí ìtàn ìjàpá àti gbogbo ọkùnrin ayé ló sọ pé ìwà ìyàwó àwọn kò dára ṣùgbọ́n ìjàpá ní ìwà ìyàwó òun ló burú jù ẹni ìyàwó rẹ̀ ń jalè sọ ìyàwó tirẹ̀ ń ṣe àgbèrè sọ ìjàpá sa ni kò sí ẹni tí ìwà ìyàwó rẹ̀ burú tó tòun Wọ́n wá ní irú ìwà wo ni ìyàwó tirẹ̀ ní tí ó mú un jẹ́ ìwà tí ó burú jù láyé? Ìjàpá sa ní ìyàwó tòun kò ní ìtìjú Ó ní ìyàwó tòun kò ní ìtìjú ní ì da gbogbo ẹ̀sẹ̀ tí wọ́n kà sílẹ̀ un oe Àwọn ìyàwó Dúrójayé ń gbìyànjú láti sọ wí pé ìyàwó tí bùrọ̀dá iléìwé Àjàní fẹ́ ní ìtìjú wí pé obìnrin tí ó bá ní ìtìjú ohun gbogbo ló ní ÀFIHÀN ÀWỌN Ẹ̀DÁ ÌTÀN Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé akópa ìtàn jẹ́ ohun kan pàtàkì nínú eréonítàn nítorí àwọn ni ọ̀nà tí òǹkọ̀wé ń lò láti gbé iṣẹ́ rẹ̀ jáde Kò sí lájọ àjọ ò kún ni àwọn ẹ̀dá ìtàn jẹ́ Nínú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà ọ̀nà tí òǹkọ̀wé gbà ṣẹ̀dá àwọn akópa rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà tí ó mú kí ìwé náà gbóúnjẹ fẹ́gbẹ́ kí ó sì tún gbàwo bọ̀ A lè pín gbogbo àwọn ẹ̀dá ìtàn inú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà sí ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ A ní olú ẹ̀dá ìtàn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀dá ìtàn àti sárépẹgbẹ́ ẹ̀dá ìtàn Olú ẹ̀dá ìtàn Àwọn wọ̀nyí ni a máa ń hun ìtàn náà mọ́ lára Olú ẹ̀dá ìtàn kì í kú tí ó bá kú ni ìtàn máa ń wá sí òpin Òun ni ìjẹyọ rẹ̀ máa ń tayọ tí àwọn yòókù Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀dá ìtàn májẹ̀óbàjẹ́ ni àwọn wọ̀nyí Bí a bá perí ajá a ó perí ìkòkò tí a fi sè é ni ọ̀rọ̀ wọn Wọ́n máa ń bá olú ẹ̀dá ìtàn ṣe wọlé wọ̀de ni wọ́n sì ń rìn súnmọ́ olú ẹ̀dá ìtàn ganan Àwọn ẹ̀dá ìtàn tí ó wà lábẹ́ ìsọ̀rí yìí nínú ìwé eréonítàn yìí ni Ṣọlábòmí Àkànkẹ́ Àríkẹ́ Èébúdọlà Jẹriogbe àti Ìyálóde Sárépẹgbẹ́ ẹ̀dá ìtàn àwọn ẹ̀dá ìtàn abẹ́ ìsọ̀rí yìí náà ń pọ̀ yanturu nínú ìtàn Wọ́n kì í ní gbòǹgbò Tí wọ́n bá tí kó ipa wọn tán wọ́n máa ń kúrò ni Àwọn ẹ̀dá ìtàn yìí máa ń mú kí ìtàn tẹ̀síwàjú ni Lára àwọn ẹ̀dá ìtàn tí ó wà ní ìsọ̀rí yìí ni Adédìran Àkànní Olúṣọlá Ọlọ́pàá méjì Kọ́lápọ̀ Adédọ̀tun àwọn ọlọ́ṣà mẹ́rin Adérìntọ́ Àdìgún ọkọ Fàwọ̀rajà Òǹkọ̀wé lo àwọn wọ̀nyí láti kópa ti wọn kí wọ́n sì fààyè sílẹ̀ fún ìdí èyí díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀dá ìtàn sárépẹgbẹ́ ni a ó ṣàlàyé nípa wọn nínú àkọsílẹ̀ yìí Dúrójayé òun ni ẹ̀dá ìtàn tí ó gbé ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà ró Àlọ́ àti ààlọ̀ inú eré náà dálórí Dúrójayé Òun ni ẹ̀dá ìtàn tí ó kópa jù láti idán kìíní títí dé ìran kẹfà eré náà ni Dúrójayé ti jẹyọ Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ni òǹkọ̀wé ti fi Dúrójayé hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò jẹ́ bí i bàbá fún Àjàní Dúrójayé Àjàní kì í kan ni ká yẹrí ó dé náà nù un àgbà tí i kan ni kì í kúkú yọwọ́ ó kan mi náà nìyẹn Tújúká Baba kú Baba kù ni Gbogbo nǹkan tí ẹ̀gbọ́n mi kò lè dúró ṣe fún ọ ni ń ó ṣe fún ọ pátápátá oe Dúrójayé ní ìyàwó meta Àkànkẹ́ Èébúdọlà Ṣọlábòmí Dúrójayé sin òkú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ó sì dúró ní ipò Baba fún Àjàní ọmọ tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi sílẹ̀ Ó ń san owó iléìwé Àjàní ó sì tún tọ́ ọ dàgbà Dúrójayé gbé ojú lógún ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kò sì pín ogún náà bí ó ti tọ́ àti bí ó ti yẹ Yàtọ̀ fún èyí Dúrójayé fúnra rẹ̀ ó mọ ẹ̀wọ́n ọ̀rọ̀ púpọ̀ àwọn ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀dọ̀ki ọ̀rọ̀ èdè awo ọfọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lo kún fọ́fọ́ sẹ́nu Dúrójayé Èyí ló fà á tí Dúrójayé fi sọ báyìí ní ìgbà tí Èébúdọlà lá àlá ọfọ̀ tí Dúrójayé pè nìyí Bo o ṣa kẹ́kẹ́ nítorí aájò ẹwà ni Bo o bàbàjà nítorí aájò ẹwà ni Ọ̀bọ̀rọ́ lOlódùmarè dá wa sayé Adia fỌ̀rúnmìlà tó lọ fẹ́ Sẹkẹtẹ obìnrin ilẹ̀ẹ́lẹ̀ Apá lòun ò pa á Ìrókò lòun ò kò ó Orúrú lòun ó rù ú Apá tólóun ó pa mi kò le pá mí mọ́ oe Dúrójayé jẹ́ aláìlójútì ẹ̀dá tí ó ń bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ lò pọ̀ Ẹni tí a fi sí ipò baba tí ó yẹ kí a máa rí àwòkọ́ṣe rere lára rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ìwà tí a bá lọ́wọ́ rẹ̀ kò dára ohun ìtìjú ni kí ó máa bá ìyàwó ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sùn Ìwà yìí jẹ́ ọ̀kan lára ìwà tí ìran Yorùbá bu ẹnu àtẹ́ lù gidi Wọ́n kà á sí èèwọ̀ wọ́n sì gbàgbọ́ pé ẹnikẹ́ni tó bá ṣe é yóò jìyà rẹ̀ Àjàní Àjàní ló tún kó ipa tí ó pọwọ́ lé ti Dúrójayé nínú ìtàn náà Òun ni ọmọ tí ẹ̀gbọ́n Dúrójayé fi sílẹ̀ sáyé Yàtọ̀ sí èyí ọmọ òkú ọ̀run ni Àjàní ń ṣe Àjàní lọ sí iléìwé ó sì jáde Ó fẹ́ ìyàwó tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àríkẹ́ A rí àpẹẹrẹ irú ènìyàn tí Àjàní jẹ́ ó máa ń bọ̀wọ̀ fún àgbà A rí àpẹẹrẹ èyí níbi tí Ìyálóde ti sọ fún Dúrójayé kí ó jẹ́ kí àwọn pe Àjàní láti bá a sọ̀rọ̀ ó ní Àjàní Sa mo ń bọ̀ sà ó wọlé ó kúnlẹ̀ níwájú wọn mo dé bàbáoe Àjàní jẹ́ ọmọ dáradára tí ó hu ìwà dáradára Nígbà tí iṣẹ́ gbé e lọ sí Gbáremú ó wá sọ fún Dúrójayé kí ó bá òun mójútó Àríkẹ́ ìyàwó rẹ̀ èyí fihàn wí pé ó nífẹ̀ẹ́ Àríkẹ́ ganan ó sì tún mọ àṣà Àjàní Kò sí nǹkan burúkú ọ̀rọ̀ ayọ̀ ni mo ní kí ń wá sọ fún yín pé wọ́n ti gbé mi lọ sí ìlú Gbáremú láti lọ ṣe olórí lọ́hùnún Ṣẹ́ ẹ sì mọ̀ pé ng kò le yára mú Àríkẹ́ lọ bẹ́ẹ̀ ni bí mo bá ní ń kọ̀ ń kò kúkú ní òkè mìíràn lẹ́hìn ọ̀run àfi kí ń dé ibi sọ oe Níbi yìí Àjàní rí Dúrójayé gẹ́gẹ́ bí bàbá rẹ̀ ó sì fún un ní ọ̀wọ̀ ni ó fi jẹ́ kí ó wá fi Àríkẹ́ lé e lọ́wọ́ Àríkẹ́ òun ni ìyàwó Àjàní Òǹkọ̀wé fi Àríkẹ́ hàn gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ìwà ọwọ́ rẹ̀ kò mọ́ Irú ìwà tí a ká mọ́ Àríkẹ́ lọ́wọ́ kì í ṣe irú ìwà tí ó yẹ kí obìnrin rere ó máa hù Ó fẹ́ ẹni tí ó jẹ́ bí i bàbá fún ọkọ rẹ̀ Dúrójayé Àríkẹ́ Kò burú bá à kú a kú ọmọ ẹni ní gbéni sin ẹ̀ẹ̀kan lèèyàn kú ṣùgbọ́n kótó di pé mo jọ́hẹn ó ku nǹkan tí o gbọdọ̀ ṣe lọ́nà kìíní a ó jọ mulẹ̀ pé awo kò ní í tú lọ́nà kejì o ó ṣe ìlérí pé ní ibikíbi tí a bá ti pàdé a ó jọ máa ṣe bí a ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ ni kí aráyé má ba à funra pàápàá àwọn ìyàwó yín oe Gbólóhùn méjì tí ó kẹ́yìn ní ìsàlẹ̀ yìí fi Àríkẹ́ hàn gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó obìnrin tí ó tún sọ wí pé a ó jọ máa ṣe bí a ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ ni kí aráyé má ba à funra pàápàá àwọn ìyàwó Dúrójayé Ní ìgbẹ̀yìn Àríkẹ́ tún sọ wí pé òun kò bá Dúrójayé sùn pọ̀ tàbí kí òun ní nǹkan pẹ̀lú rẹ̀ Òǹkọ̀wé ṣe àfihàn Àríkẹ́ gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí kò ṣe é fi yangàn láwùjọ nítorí irú obìnrin tirẹ̀ kò le mú ìdàgbàsókè bá àwùjọ Ìyálóde Ìyálóde jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ará àdúgbò Dúrójayé tí ó pè láti wá bá òun pín ogún tí ẹ̀gbọ́n òun fi sílẹ̀ Òǹkọ̀wé ṣe àfihàn Ìyálóde gẹ́gẹ́ bí alátẹnujẹ ẹ̀dá nítorí ẹni tí a bá pè ní Ìyálóde gbọdọ̀ hu ìwà tí àwọn ọmọlẹ́yìn tàbí ará àdúgbò máa le mú yangàn láwùjọ Ní ìgbà tí Ìyálóde pín ogún tán ó tún bèèrè ẹ̀tọ́ tirẹ̀ lọ́wọ́ Dúrójayé ó wí báyìí Ìyálóde ó dára mo fara mọ́ ọn ṣùgbọ́n o mọ̀ pé iṣẹ́ ńlá ni mo bá ọ ṣe ùn nì kí ni èrè tèmi oe Àkànkẹ́ Ṣọlábòmí Èébúdọlà àwọn wọ̀nyí jẹ́ ìyàwó fún Dúrójayé Ṣọlábòmí ni ìyálé ó sì máa ń hu ìwà tí ó yẹ kí ìyálé hù A rí àpẹẹrẹ ohun tí Ṣọlábòmí ṣe nígbà tí Èébúdọlà lá àlá nípa ọkọ rẹ̀ wí pé ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà Ṣọlábòmí gbé ìgbésẹ̀ tí ó lágbára ó ran Àkànkẹ́ àti Èébúdọlà lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá awo Ṣọlábòmí Ẹ ṣeun ọ̀rọ̀ púpọ̀ irọ́ ní mú wá Ìwọ Àkànkẹ́ àti Èébúdọlà ẹ wá jọ lọ kẹ́ sì padà ní kíákíá kí baálé wá tó dé Ṣe ẹ mọ̀ pé kò gbọdọ̀ mọ̀ pé a ń tojúlé aláwo ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ yìí tí kúrò ní wàsá ó ti di hun kí gbogbo wa ó múra ni ìrọ̀rùn igi ni ìrọ̀rùn ẹyẹ àwọn méjèèjì Àkànkẹ́ àti Èébúdọlà dìde wọ́n sẹ́sọ lórí ó di lé Adífásẹ lóòjọ́ baba awo Ẹ má gbàgbé pé bí ó bá ní ìrànlọ́wọ́ tí bàbá awo bá lè ṣe kó ṣe é ní kíakíá ni o oe Òǹkọ̀wé ṣe àfihàn àwọn ìyàwó Dúrójayé gẹ́gẹ́ bí ìyàwó gidi ní ọ̀ọ̀dẹ̀ ọkọ wọn wọ́n gbárùkú ti ọkọ wọn Wọ́n sì fi ọwọ́ sowọ́pọ̀ Yorùbá gbàgbọ́ pé ilé olórogún ilé ariwo ni ṣùgbọ́n tiwọn kò rí bẹ́ẹ̀ Ìfẹ́ wà láàárín àwọn ìyàwó mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí Dúrójayé ní a sì lè sọ wí pé ìfẹ́ yìí ló jẹ́ kí ilé wọn dùn Nígbà tí ọkọ wọn wọ wàhálà ní àgọ́ Ọlọ́pàá wọ́n tún wá ọkọ wọn débẹ̀ wọ́n sì tún ṣe onídùúró fún un ní àgọ́ Ọlọ́pàá Èébúdọlà Ó yá ẹ jẹ́ a jọ máa lọ ọ̀rọ̀ kì í kan ni tán ká tún máa yẹrí Ẹ jẹ́ a jọ máa lọ ṣe bí ilé ìyàwó ni? Ó ti yá oe Ẹ̀bùn àlá lílá tí Èébúdọlà ní ni ó jẹ́ kí wọ́n wá ọ̀nà àbáyọ sí ìsọ̀rí náà ṣùgbọ́n ọkọ wọn kọ etí ikún sí ìmọ̀ràn Adífá Èébúdọlà lá àlá wí pé àwọn ọlọ́ṣà mú ọkọ òun gẹ́gẹ́ bí olè Èébúdọlà Ó ké láti ẹ̀hìn ìtàgé lọ́hùnún irọ́ ẹ̀ ò ní mú un lọ òun kì í ṣe ará àwọn olè wọ̀nyí rárá kò lọ ó lọgun sí ìta kò lọ kì í ṣe olè ṣe é Ẹ gbà mí wọ́n fẹ́ mú baálé wa lọ nìyí Kò lọ o oe Èsì tí Dúrójayé fún àwọn ìyàwó rẹ̀ nípa àlá yìí ni wí pé àlá gọ̀ ẹ̀rù kì í ba olóṣèlú Ó sọ báyìí Dúrójayé Ẹ má jẹ́ kí ń bínú sí yín o Àwa òṣèlú kì í wà nínú báun Ẹni tóbá wà nínú òṣèlú kò le fẹ́ irú nǹkan ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ kù Ẹrù kì í ba àwa Ẹní kóṣèlú má jáde alẹ́ ẹ ò mọ̀ pé alẹ́ lòṣèlú ń rìn alẹ́lòṣèlú ń ṣe ìpàdé wọn Kò séwu ẹ lọ fọkàn balẹ̀ Ohun tí Dúrójayé ń sọ ni pé àwọn olóṣèlú máa ń rin ìrìn alẹ́ olóṣèlú sì ni òun náà wí pé kò sí bí òun kò ṣe ní rìnrìn alẹ́ wí pé kí àwọn ìyàwó òun lọ fi ọkàn balẹ̀ Ọlọ́ṣà Mẹ́rin àwọn wọ̀nyí ni àwọn olè tí wọ́n pàdé Dúrójayé ní ojú ọ̀nà Òǹkọ̀wé ṣe àfihàn wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n máa ń rìn lóru tí wọn kò ní iṣẹ́ kan pàtó tí wọ́n ń ṣe ÌLÒ ÈDÈ Èdè ni òǹkọ̀wé ń lò láti bu ẹwà kú iṣẹ́ rẹ̀ Nínú gbogbo àwọn òǹkọ̀wé òde òní kò sí èyí tó tún ń fèdè dárà bí i Fágúnwà Òkédìjí àti Adébáyọ̀ Fálétí ṣùgbọ́n bí èdè ṣe máa ń gun àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yàtọ̀ sí ara wọn Fágúnwà máa ń ṣe àgbékalẹ̀ bátànì ìwọ̀nba ni òwe òun ló sì máa ń lo àlòtúnlò bátànì ó máa ń lo àkànlò èdè lóríṣìíríṣìí ó máa ń pa kádàrá òwe dà Adébáyọ̀ Fálétí a máa lo èdè bí ìgbà tí a ń wo fíìmù ó máa ń lo èdè ojú ayé Ní ti Olú Owólabí ó mọ́ èdè lò dáadáa ọnà èdè ló jẹ́ kí ìwé eréonítàn rẹ̀ dùn kí ó sì wuni Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ló fi sọ àkọlé ìwé rẹ̀ Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà Ó fẹ́rẹ̀ máà sí ojú ìwé kan tí kò sí òwe níbẹ̀ Ó tún lo àfiwé lóríṣìíríṣìí àkànlò èdè ọfọ̀ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ gbogbo ọnà èdè wọ̀nyí ló kún sínú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà ṣùgbọ́n òwe ló pọ̀ jù Kò yani lẹ́nu pé Olú Owólabí lo àwọn ọnàèdè wọ̀nyí bẹ́ẹ̀ nítorí òun funra rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ àgbà ó sì gbé àwùjọ Yorùbá Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mẹ́nubà á nínú ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ Gbogbo ọnàèdè wọ̀nyí ló mú kí àgbékalẹ̀ àwọn gbólóhùn rẹ̀ lágbára kí wọ́n sì dùn ún gbọ́ ÒWE Òwe jẹ́ ọ̀nà èdè pàtàkì tí oníṣe ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ máa ń lò Yorùbá ka òwe kún ọ̀rọ̀ ẹnu àgbà ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé tí ọmọdé bá fẹ́ pa òwe ó ní láti júbà àwọn àgbà Á ní; Ọmọdé tótó ṣebí òwe ẹ̀yin àgbà Àgbà ò ó pa òmíràn Yorùbá a máa fi òwe sọ̀rọ̀ wọ́n lè fi òwe bínńtín yanjú ọ̀rọ̀ bàǹtabanta ọmọ Yorùbá tó bá mọ́ nípa òwe àti ìlò rẹ̀ wọ́n a máa bọ̀wọ̀ fún un láwùjọ Bí èyí tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ a níláti fi kún un pé aṣeburúkúṣerere ni òwe A lè fi òwe dá wàhálà sílẹ̀ Èyí wọ́pọ̀ nílé olórogún tàbí láàárín àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú Orogún méjì a máa fi òwe tàbùkù ara wọn Bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ́ òṣèlú kan a máa fi òwe tàbùkù alátakò wọn Wọ́n lè sọ ọ́ lọ́rọ̀ ẹnu tàbí kí wọ́n kọ ọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ni èyí máa ń dá yánpọn yánrin sílẹ̀ Dúrójayé lo òwe ní ìgbà tí ó ń pàrọwà sí Àjàní wí pé òun yóò ṣe bí baba fún un Lára àwọn òwe tí ó pa ni Ayé tí ẹsin kò le jẹ ìrù ìdí rẹ̀ yóò jẹ ẹ́ Kò séwu lóko àfi gìrì àparò Dúrójayé pa òwe yìí láti fi mú inú Àjàní dùn kí ó má ba à máa ronú mọ́ Yàtọ̀ fún èyí Dúrójayé tún pa òwe mìíràn ní ibi tí wọ́n ti ń pín ogún ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ó ní Ìka tóbá tọ́ sí imú là á fi rè é Ẹ dúró àìsí níbi ọ̀rọ̀ làì dási í Ẹ jẹ́ a na sùúrù sí i kí a fi egungun òtòlò tò ó oe Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ò kágbọ̀n afẹ́fẹ́ ní gbé e lọ oe Sàkó là sọ̀rọ̀ ajé ní í mú ni pẹkọrọ Ọbẹ̀ tó dùn owó ló pa á oe Ẹni a ní kó kín ni lẹ́hìn ẹ̀gún ló fi sọ́wọ́ ẹni a ní kó fẹ́ ni lójú ata ló fi sẹ́nu Bọ́wọ́ ò bá tẹ èèkù idà a kì í bèèrè ikú tó pa baba ẹni Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ là á fi í pa àmúkùrù abẹ́ ẹni bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ó le lọ di ẹtike Bí kò bá ní ìdí obìnrin kì í jẹ́ kúmólú oe Ojú àwo làwo fi gbọbẹ̀ oe ÀFIWÉ Àfiwé jẹ́ irúfẹ́ ọnà èdè kan tí ó ṣe pàtàkì nínú lítíréṣọ̀ àpilẹ̀kọ lápapọ̀ Àfiwé jẹ́ fífi ohun méjì wé ara wọn Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ohun tó bá jọra là á fi wéra èpo ẹ̀pà ló jọ pósí ẹ̀lírí Èyí ni pé tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àfiwé a nílò láti fi ohun méjì wéra Ọ̀nà méjì ni a lè pín àfiwé sí àwọn náà ni; àfiwé tààrà àti àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ Nínú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà àfiwé tààrà ni a rí púpọ̀ Àfiwé tààrà sì ni fífi ohun méjì wéra wọn nípa lílo atọ́ka bí A rí àpẹẹrẹ ní ibi tí Jẹ́nrìogbé ti ń bá Àjàní sọ̀rọ̀ lórí ogún bàbá rẹ̀ ó ní; Jẹ́nrìogbé Ìyẹn lowá ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ bí ojú ewé omi oe Òun ni ó ti tún gba nǹkan ẹ̀ pé pátápátá niṣe ló ń ta sọ́tùnún ta sósì bí iṣu ìbàrìbà oe Ní ibi ayò Àkànní sọ báyìí sí Ràímì Ẹjọ́ wo sá ta koto máa sọ ìṣọkúṣọ bí ẹja lómi oe Bákan náà ní ìgbà tí Dúrójayé ń sọ pé ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin kò ju owú lọ Èébúdọlà sọ báyìí Èwo lẹ̀yin náà wá múra bí i kọ̀pákọ̀pá Ikirun sí oi Òwe pọ̀ nínú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà èyí ló sì jẹ́ kí ìwé náà dùn kó sì lárinrin Tí òǹkọ̀wé Olú Owólabí kò bá ṣe àmúlò òwe nínú ìwé náà yóò kàn rí sákálá ORIN Orin jẹ́ ọ̀kan lára ewì alohùn Yorùbá tí òǹkọ̀wé le mú lò yálà láti gbé èrò kan yọ tàbí láti fi adùn kún iṣẹ́ wọn Orin gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ jẹ́ ara àjẹbí Yorùbá Ní gbogbo ìgbà àti ní ibikíbi ni Yorùbá tí máa ń lo orin Òǹkọ̀wé lè lo orin ní ìbẹ̀rẹ̀ àárín tàbí ní ìparí ìwé wọn Oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni a lè gbà lo orin ṣùgbọ́n ohun tó kàn wà nínú iṣẹ́ yìí ni ọ̀nà tí Olú Owólabí gbà ṣe àmúlò orin nínú Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà A máa ń lo orin níbi ọdún ayẹyẹ ìpolówó ọjà ìbò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Nígbà mìíràn àwọn Babaláwo pẹ̀lú máa ń kọrin èyí sì ni orin ifá Ní ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n bá fẹ́ sin òkú ó di dandan kí wọn kọrin níbẹ̀ irú èyí náà ni Olú Owólabí ṣe àmúlò nínú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà níbi tí wọ́n ti fẹ́ sin òkú ẹ̀gbọ́n Dúrójayé ìyẹn bàbá Àjàní Ilé ló lọ tàràrà Ilé ló lọ tàràrà Bàbá Àjàní re lé o Ilé ló lọ tàràrà oe Ohun tó ṣe okùnfà orin yìí ni ikú ẹ̀gbọ́n Dúrójayé wọ́n sì kọ orin náà níbi ìsìnkú rẹ̀ Òǹkọ̀wé tún fi orin sẹ́nu Jẹ́nrìogbé ní ìgbà tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ wí pé Àjàní rí iṣẹ́ ní báǹkì ńlá ti ìjọba Ẹ jẹ́ ó gbáyé Ẹ jẹ́ ó gbáyé Ẹ jẹ́ ó gbáyé Jẹ́nrìogbé ẹ jẹ́ ó gbáyé oe Orin yìí tí Jẹ́nrìogbé hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọ̀dọ̀ tí ara tù tí ó sì ti fẹ́rẹ̀ di ọmọ onílé nítorí náà ó máa ń ṣe àyọnusọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà Dúrójayé náà tún kọrin Èmi la ò ní í yọ̀ sí? Èmi la ò ní í yọ̀ sí? Báa ṣe fẹ́ ó rí Bẹ́ẹ̀ náà lórí Èmi la ò ní í yọ̀ sí? oe A ó rí wí pé orin tí Dúrójayé ń kọ yìí inú rẹ̀ kò dùn sí i ojú ayé ló ń lò Ó kọ orin yìí níbi ayẹyẹ wí pé Àjàní ríṣẹ́ ní báǹkì ó sì tún jáde ìwé mẹ́wàá Oríṣìí orin mìíràn tí òǹkọ̀wé tún ṣàmúlò ni orin ìfẹ́ ní èyí tí ó fi sẹ́nu Àríkẹ́ A rí àpẹẹrẹ èyí ní idán karùnún ní ìgbà tí ó wà ní ilé tí ó ń múra lọ́wọ́ Àríkẹ́ Wèrèpè gba ra ẹ̀ lọ́wọ́ mi o Alájàní gba ra ẹ̀ lọ́wọ́ mi o Ng ó rè lemi nile Àjàní o Ng ó rè lemi nile Àjàní o Àjàní ọ̀gọ́ ojú la ń tì fún ra wa Àjàní ọ̀gọ́ ojú la ń tì fún ra wa o Ng ó rè lemi nile Àjàní o Gba reterete o àwa gba ra dà o Gba reterete o àwa gba ra dà o oe Ní ìparí ìwé náà òǹkọ̀wé tún ṣàmúlò orin ó fi orin yìí sẹ́nu Àjàní Ènìyàn ó ṣe finú hàn Bóba lọ́gbọ́n fi síkùn ara rẹ Ènìyàn ò ṣe finú hàn Bóba lọ́gbọ́n fi síkùn ara rẹ Pẹ̀lú èyí Ẹ yé máa dalẹ̀ o Ẹ yé máa dalẹ̀ o Ẹ yé máa dalẹ̀ o Ọ̀dàlẹ̀ bálẹ̀ lọ o oe Orin ìparí yìí jẹ́ kí a mọ̀ wí pé ọ̀dàlẹ̀ kò pé irú ìwà tí Dúrójayé hù kò dára kò sí yẹ láwùjọ ọmọlúàbí ÀKÀNLÒ ÈDÈ Òǹkọ̀wé lo èyí náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti gbé adùn èdè Yorùbá yọ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé Yorùbá kì í sọ̀rọ̀ sákálá Ìlò ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkànlò èdè jẹ́ ọ̀kan nínú ọ̀nà tí òǹkọ̀wé ń gba wọ́nyọ̀ sí ìtàn rẹ̀ Lára àwọn àkànlò èdè bẹ́ẹ̀ ni wọ̀nyí Ó sì baralẹ̀ èyí túmọ̀ sí pé ó fi ara balẹ̀ oe Fàáké kọ́rí èyí túmọ̀ sí pé kọ̀ jálẹ̀ oe Ọ̀rọ̀ kí sẹ̀sẹ̀ rago èyí túmọ̀ sí pé nǹkan kí síbẹ̀ oe Àkàrà tú sépo èyí ni pé àṣírí tú oe ÌJÌNLẸ̀ Ọ̀RỌ̀ Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ní ìtumọ̀ tó farasin Èyí tí ó jẹ́ pé bí ìmọ̀ ènìyàn kò bá gbámúṣé nínú èdè Yorùbá yóò sòro fún irú ẹní bẹ́ẹ̀ láti mọ ìtumọ̀ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ Àpẹẹrẹ èyí ni a rí nígbà tí Asiyanbi àti àwọn yòókù rẹ̀ fẹ́ bá Dúrójayé pín ogún ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ó ní; Dúrójayé Sako la a sọ̀rọ̀ ajé ní í mú ni pẹkọrọ oe Díẹ̀ lára àwọn ọnà èdè tó súyọ nínú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà ni a ti mẹ́nubà wọ̀nyí Òwe ni ọnà èdè tó kira jù nínú ìwé eréonítàn náà Òǹkọ̀wé fi òwe já iṣẹ́ rẹ̀ bí ìgbà tí a bá fi irú já ọbẹ̀ Ó sì jẹ́ kí ìwé náà dùn A le rí bí òwe ogójì nínú ìwé náà tí àwọn ọnà èdè tókù kò sí tó bẹ́ẹ̀ ORÍ KẸ́RIN TÍỌ́RÌ ÌṢÀMÚLÒ TÍỌ́RÌ ÌFOJÚ ÀṢÀ ÌBÍLẸ̀ WO IṢẸ́ LÍTÍRÉṢỌ̀ ERÉONÍTÀN ÀGBÀ TÍ Ń YỌ́LẸ̀ DÀ ÌFÁÀRÀ Ní abala yìí a ó wo ipa tí àṣà ìbílẹ̀ kó nínú iṣẹ́ òǹkọ̀wé A fẹ́ mọ àwọn àṣà Yorùbá tó jẹyọ àti ìhà tí òǹkọ̀wé fúnra rẹ̀ kọ sí i A fẹ́ mọ̀ bóyá òǹkọ̀wé gbé àṣà lárugẹ ni tàbí ó bu ẹnu àtẹ́ lù ú Èyí tó wù kó jẹ́ a níláti wádìí ohun tí ó mú kí òǹkọ̀wé ṣe bó ṣe ṣe TÍỌ́RÌ ÌFOJÚ ÀṢÀ ÌBÍLẸ̀ WO IṢẸ́ LÍTÍRÉṢỌ̀ ÀTI ERÉONÍTÀN ÀGBÀ TÍ Ń YỌ́LẸ̀ DÀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mẹ́nubà sáájú ohun tí tíọ́rì àṣà ìbílẹ̀ dálé ní láti gbé àṣà Yorùbá lárugẹ àti láti mú àṣà wá sí ìrántí Àwọn agbátẹrù tíọ́rì yìí pín àṣà sí ọ̀nà méjì àwọn ìṣọ̀wọ́ kìíní rí àṣà gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò gbọdọ̀ yípadà Àṣà tí kò sayé lóore ni wọ́n sì ń gùnlé irú àkójọpọ̀ àṣà bẹ́ẹ̀ kì í fẹ́ ìjà kì í fẹ́ ìta kí a sáà máa wòran kí a máa bẹ̀rù àgbà kí a bẹ̀rù àwọn ajunilọ bí wọ́n tilẹ̀ ń fọwọ́ ọlá gbá wa lójú Ìṣọ̀wọ́ kejì ni àwọn tó gba àṣà ni ohun atáyéṣe àkójọpọ̀ àṣà tí ó lè tanijí tí ó lè gún àwọn mẹ̀kúnnù ní kẹ́ṣẹ́ inú láti dìde fún ìjàgbara ni wọ́n ń kójọ Bákan náà wọn rí àṣà gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣe é fi yangàn láwùjọ Irú àṣà bẹ́ẹ̀ lo yẹ kí òǹkọ̀wé máa ṣe àwárí àti àfihàn nínú iṣẹ́ ọnà rẹ̀ Ìsọ̀wọ́ kìíní ni a ó mú lò nínú iṣẹ́ yìí àṣà tí ó bá tíọ́rì yìí mu ni àṣà ogún pínpín Àṣà ogún pínpín ní ilẹ̀ Yorùbá ó di dandan tí ènìyàn bá kú kí wọ́n pín ogún rẹ̀ fún àwọn tí olóògbé fi sílẹ̀ ÀṢÀ ÌKÓBÌNRINJỌ Láwùjọ Yorùbá bí wọ́n tilẹ̀ máa ń fẹ́ obìnrin tó pọ̀ síbẹ̀ wọ́n gbàgbọ́ pé ilé olórogún ilé wàhálà ni nítorí pé òòṣà jẹ́ ń pé méjì obìnrin kò dénú Nínú odù ifá ọ̀yẹ̀kú méjì a rí èrò Yorùbá nípa obìnrin tó sọ pé; Obirin lèké Obìnrin lọ̀dàlẹ̀ Kéèyàn má finú hàn fóbìnrin Èyí túmọ̀ sí pé obìnrin bímọ fún ní kò pé kò má pani àti pé odù yìí jẹ́ kí a rí wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tó le tí kò ṣe é fojú bínńtín wò Bí Yorùbá tilẹ̀ gbàgbọ́ wí pé kò yẹ kí a fi àṣírí hàn obìnrin síbẹ̀ ohun èlò kòseémáàní ni wọ́n jẹ́ Láì sí obìnrin kò le sí ọkùnrin nítorí obìnrin náà ló bí ọkùnrin Ìwúlò obìnrin ní àwùjọ kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn ìyàwó Dúrójayé kò rí bẹ́ẹ̀ Kò sí ìjà láàárín àwọn ìyàwó Dúrójayé Wọ́n mú ara wọn bí tẹ̀gbọ́n tàbúrò Àwọn ìyàwó Dúrójayé gbárùkù ti ọkọ wọn Nígbà tí Èébúdọlà ọ̀kan nínú wọn lá àlá pé àwọn ọlọ́ṣà mu ọkọ wọn Ṣọlábòmí èyí tó jẹ́ àgbà rán Àkànkẹ́ àti Èébúdọlà lọ sí ọ̀dọ̀ adífá láti lọ bèèrè lọ́wọ́ ifá Wọ́n gbàgbọ́ pé ìrọ̀rùn igi ni ìrọ̀rùn ẹyẹ Ohun tó bá débá ojú ó ti dé bá imú Bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tó bá débá baálé wọn ó ti débá àwọn pẹ̀lú Ṣọlábòmí wí báyìí Ẹ seun ọ̀rọ̀ púpọ̀ irọ́ ní í mú wa ìwọ Àkànkẹ́ àti Èébúdọlà ẹ wa jọ lọ kẹ sì padà ní kíákíá kí baálé wa tó tòde dé Ṣe ẹ mọ̀ pé kò gbọdọ̀ mọ̀ pé a ń tọjúlé aláwo oe Bakana náà ètùtù tí Adífásẹ ní kí wọ́n pèsè wọn ṣe ní kánmọ́kánmọ́ wọn kò tilẹ̀ dúró kí baálé wọn fi dé A tilẹ̀ ti ṣe ètò láti ṣe gbogbo ètùtù ibẹ̀ èyí tí ó ṣe pàtàkì ni pé wọ́n ní kí ẹ má rìn lóru àti pé kí ẹ sọ́ra òde alẹ́ nítorí ogun àdúnrunmọ́ ojú lalákàn fi ń sọ́rí Bí èèyàn bá sì gbọ́ nǹkan tán ọ̀rọ̀ bùṣe nù Àwọn ìyàwó Dúrójayé kò mú Àjàní gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀gbọ́n ọkọ wọn wọ́n mú un gẹ́gẹ́ bí ọmọ wọn Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé ní ilé olórogún oníkálùkù pẹ̀lú tirẹ̀ ni ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ ní ti àwọn ìyàwó Dúrójayé Nígbà tí àwọn Ọlọ́pàá mú Dúrójayé àwọn ìyàwó rẹ̀ tún gba lọ́yà fún un wọ́n kò fi ọkọ wọn sílẹ̀ títí ọjọ́ ìdájọ́ irú ìwà báyìí kò wọ́pọ̀ nílé olórogún Òǹkọ̀wé ń gbìyànjú àti sọ fún wa pé kò sí ohun tó burú nínú kí a kó obìnrin jọ Bí a bá tilẹ̀ kápá wọn nítorí ọgbọ́n tí a fi ń kọ́lé kò tó èyí tí a fi ń gbénú rẹ̀ Ó níláti jẹ́ pé Dúrójayé tí ṣe àwọn ìyàwó rẹ̀ lọ́kàn láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ÀṢÀ ÌBỌ̀WỌ̀ FÁGBÀ Ọ̀kan pàtàkì lára ìwà ọmọlúàbí tí Yorùbá káràmásìkí jùlọ ni ìbọ̀wọ̀ fágbà Èyí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ẹ̀kọ́ ilé tí Yorùbá máa ń fún ọmọ wọn Yorùbá gbàgbọ́ pé bí a ṣe níláti kẹ́ ọmọ tí a bá bí bẹ́ẹ̀ náà ni a ṣe ní láti kọ́ ọmọ tí kì í ṣe tiwa Nínú ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà a rí Àjàní ọmọ òrukàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ Yorùbá gidi ó bọ̀wọ̀ fún àgbà ó tún bọ̀wọ̀ fún àwọn ìyàwó ilé pàápàá Yorùbá bọ̀ wọ́n ní abẹ̀rù àgbà ni yóò tẹ ilẹ̀ pẹ́ Kò ya ni lẹ́nu pé Àjàní mókè nítorí ó bọ̀wọ̀ fún àgbà ni Nígbà tí Dúrójayé pe Àjàní ó dáhùn báyìí Ẹ ṣeun ń kò ni àṣẹ kan lẹ́hìn èyí tí bàbá bá ti ṣe ṣe bí àwọn náà ni wọ́n sá à kù ní baba fún wa? Ó ti parí Ibi tí ẹ bá parí rẹ̀ sí náà ló parí sí? Ẹ ṣeun baba ṣe ń máa lọ àbí ọ̀rọ̀ kù? ó dìde ó dọ̀bálẹ̀ oe Dúrójayé pàápàá jẹ́rìí sí pé Àjàní dára ó ní; Àjàní dára kì í ta àgbà lẹ́nu kì í sì hùwà ọ̀dàlẹ̀ kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó ní òdodo lẹ́nu oe Bákan náà nígbà tí Àjàní mú Àríkẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Dúrójayé ó dọ̀bálẹ̀ Àríkẹ́ náà kúnlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì ìbọ̀wọ̀ fún ẹni tó junilọ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mẹ́nubà sáájú òǹkọ̀wé ń fi yé wa pé bó ti wù kí ọ̀làjú pọ̀ tó àṣà yìí kò le yipada Ìgbàgbọ́ yìí sì wà pé ọmọdé tí kò bá bọ̀wọ̀ fún àgbà kò le ṣe àṣeyọrí kan láyé ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń gbàdúrà pé kí àgbà máa tán lórílẹ̀ ÀṢÀ IFÁ DÍDÁ Ifá jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ìbọ Yorùbá Ní ilẹ̀ Yorùbá tí nǹkan bá rújú ọ̀dọ̀ ifá ni a ti lè bèèrè Ìgbàgbọ́ yìí náà ni àwọn ìyàwó Dúrójayé ní tí wọ́n fi lọ sí ọ̀dọ̀ Adífáṣẹ láti wá ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro ọkọ wọn Àwọn ìyàwó Dúrójayé tọ ẹlẹ́rìí ìpín lọ wọ́n kò ja ifá níyàn kíákíá ni wọ́n ṣe ohun gbogbo tí ifá ní kí wọ́n ṣe nítorí Yorùbá bọ̀ wọ́n ní rírú ẹbọ ní í gbeni àìrú ẹbọ kì í gbènìyàn Lẹ́yìn tí Adífáṣẹ ti ki ifá tán ó ka ẹbọ fún wọn ó ní; Ètùtù rẹ̀ kò pọ̀ bí ẹ bá ti le ṣe é kí ẹ mú odindi garawa epo kan wá kí ẹ mú ewúrẹ́ kan wá kí ẹ wá mú gbogbo nǹkan tí ẹnu ń jẹ wá a ó fi ṣe ètùtù ni Ìpèsè fún àwọn ayé ni a ó fi ṣe oe Nígbà tí Àkànkẹ́ àti Èébúdọlà délé wọ́n jíṣẹ́ fún ìyálé wọn òun náà dá wọn lóhùn ó wí pé; Ẹ dúró bíṣẹ́ ó bá pẹ́ ni a kì í pẹ́ṣẹ́ Ìwọ Àkànkẹ́ dúró kí o gba owó kí o lọ ra gbogbo nǹkan tí wọ́n wí kó o sì rí i pé o ṣe gbogbo ètùtù yẹn kí o tó padà wá sí lé Ṣọlábòmí wọ ilé ó fún Àkànkẹ́ ní owó Àkànkẹ́ jáde oe Ní ìgbẹ̀yìn gbogbo rẹ̀ Dúrójayé kọ etí ikún sí ọ̀rọ̀ ifá ó pawo lékèé ó pèsù lólè Dúrójayé rí ara rẹ̀ bí ẹni tí kò ní kú mọ́ ó ní; Èmi tí mo ti wà nínú òṣèlú fún ọjọ́ pípẹ́ ṣé nǹkan kékèèké báyìí ló tún yẹ kó tún dá ẹ̀rù bà mí Ẹ̀rù ò bodò ẹni tí yóò wọ odò lominu ń kọ Mo mọ̀ pé ọ̀tá wà nítọ̀ọ́tọ́ ṣùgbọ́n èmi náà kò kúkú túra sílẹ̀ oe Òǹkọ̀wé fi yé wa pé kò yẹ kí ọ̀làjú òde òní gba irú àṣà báyìí sọnù lọ́wọ́ wa Ó fi àtunbọ̀tán àìbìkítà Dúrójayé ṣàlàyé Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ló ń ṣokùnfà púpọ̀ nínú wàhálà tó wà láwùjọ wa lónìí Òǹkọ̀wé ṣe ìgbélárugẹ fún àṣà ifá dídá ÀṢÀ AYÒ TÍTA Lẹ́yìn iṣẹ́ òòjọ́ ni Yorùbá máa ń ta ayò ní ilẹ̀ Yorùbá Yorùbá gbàgbọ́ pé òǹrayè ènìyàn ló máa ń fi àárọ̀ tayò Èyí ni pé ìran Yorùbá lòdì sí fífi àárọ̀ ẹni ṣeré Yorùbá bọ̀ wọ́n ní eré là á fọmọ ayò ṣe Ní ìdí ayò oríṣìíríṣìí ẹ̀fẹ̀ àwàdà yẹ̀yẹ́ ṣíṣe ló máa ń wáyé pàápàá láti ẹnu àwọn òṣẹ̀fẹ̀ ayò Bákan náà ìdí ayò ni àti máa ń mọ ọ̀pọ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ Òǹkọ̀wé faramọ́ ìgbélárugẹ àṣà yìí nítorí àǹfààní tó pọ̀ ló wà níbẹ̀ Ohun tí Ràímì sí nídìí ayò túbọ̀ jẹ́ kí a mọ irú ènìyàn tí Dúrójayé jẹ́ ganan níbẹ̀ ni a ti rí i pé ọ̀bàyéjẹ́ àti aláìnítìjú ènìyàn ni Lára ìwà tí Yorùbá gbàgbọ́ pé ó burú jù olè jíjà lọ ni kí a bá ìyàwó ọmọ ẹni ní àjọsepọ̀ Ayé ó le yípadà débi pé kí a fi fìlà dé ìdodo Kò sí àwáwí tí Dúrójayé le ṣe tó lè mú un gba ìdáríjì Adájọ́ pàápàá sọ èyí nígbà tí ó wí pé; Ẹ̀yin ti gbàgbé pé bí ènìyàn bá ń fi nǹkan pamọ́ ó gbọdọ̀ rántí ẹní tí ó le wá a kí ó rí i Bí wọ́n ti gbọ́n nílé ọkọ ni wọ́n gbọ́n nílé àlè oe ÀṢÀ OGÚN PÍNPÍN Tí ènìyàn bá ku ó di dandan kí wọ́n pín ogún tí ó fi sílẹ̀ sáyé Ní ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá àwọn ẹbí tàbí ẹni tí ó bá jẹ́ olórí ẹbí ni ó lẹ́tọ̀ọ́ láti sètò ogún pínpín Àwọn ọmọ ìyàwó àti àbúrò olóògbé ló lẹ́tọ̀ọ́ sí ogún Dúrójayé kọ̀ láti pín ogún fún àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ nítorí ó jẹ́ arẹ́nijẹ ọ̀kánjúà àti olójúkòkòrò ẹ̀dá Lẹ́yìn tí Akíndélé àti àwọn yòókù ti bínú kúrò lọ́wọ́ wọn Ìyálóde bèèrè báwo ni Dúrójayé ṣe fẹ́ kí wọ́n pín ogún náà Dúrójayé dáhùn ó ní Kò sí ọ̀rọ̀ kan gbogbo ogún yìí ni mó fẹ́ ẹ́ jẹ kí ń sì rí i pé Àjàní parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni iléìwé gíga tówà Bóbá wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ a lè fún un ní díẹ̀ nínú ogún náà oe Ìwà tí Ìyálóde hù burú nítorí òun ni ó yẹ kí ó máa ṣe àmójútó ìlú ó tún wá ń balẹ̀ jẹ́ ó lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Dúrójayé láti fún Àjàní ní díẹ̀ nínú ogún náà A rí ẹ̀rí ohun tí Ìyálóde fẹ́ gbà nídìí ìfọwọ́ṣowọ́pọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Dúrójayé Nígbà tí ó bèèrè lọ́wọ́ Dúrójayé pé; Ó dára mo fara mọ́ ọn ṣùgbọ́n o mọ̀ pé iṣẹ́ ńlá ni mo bá ọ ṣe un kí ni èrè tèmi oe Ìhùwàsí Ìyálóde fihàn pé kò sí ẹnìkan tó ṣe é fẹ̀hìntì Àwọn ìjòyè tó yẹ kí wọ́n máa ṣe ètò bí ìlú yóò ṣe tùbà tí yóò tùṣẹ tí àlàáfíà yóò sì jọba láàárín àwọn ènìyàn ni a tún bá nídìí mọ̀dàrú Èyí só sí ni lẹ́nu ó tún bu iyọ̀ sí Òǹkọ̀wé wá ń bèèrè ọ̀nà àbáyọ nínú ìlànà ogún pínpín ti igbalode níbi tí oní nǹkan yóò ti ṣe ìwé sílẹ̀ kí ó tó kú Èyí tó wù kó jẹ́ òǹkọ̀wé jẹ́ kí a gbàgbọ́ pé ẹni tí kò bá ṣe é bí wọ́n ti í ṣe é àtunbọ̀tán rẹ̀ kì í dára A rí ẹ̀rí èyí nínú ohun tó gbẹ̀yìn Dúrójayé ÀṢÀ ÌWỌṢỌ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé Yorùbá káràmásìkí aṣọ wíwọ̀ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní aṣọ ni iyì ènìyàn díẹ̀ lára aṣọ Yorùbá nìwọ̀nyí dàńdógó gbárìyẹ̀ agbádá sapara dàńsíkí bùbá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Yorùbá máa ń wọ aṣọ láti dáàbò bo ara wọn Ẹ̀wù tí Dúrójayé fi hàn gẹ́gẹ́ bí olówó ọlọ́lá àti ènìyàn pàtàkì láwùjọ Nígbà tí ẹ̀wù Àjàní wọ fi í hàn gẹ́gẹ́ bí alákọ̀wé òṣìṣẹ́ ọba Èyí túmọ̀ sí pé òǹkọ̀wé lo ẹ̀wù tó bá ipò ààyè olúkúlùkù mu ÀṢÀ ÀLEJÒ ṢÍṢE NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ Bí ènìyàn bá wá kí ọmọ Yorùbá ó tọ́ ó sì yẹ kí a ṣe wọ́n lálejò Bí àpẹẹrẹ ọtí àti oúnjẹ ni a fi ń ṣe àlejò àgbà Olú Owólabí ṣe àmúlò àṣà yìí níbi ayẹyẹ ìparí ìwé mẹ́wàá Àjàní àti pé ó tún rí iṣẹ́ sí ilé ìfowópamọ́nla ti ìjọba Níbi ayẹyẹ yìí wọ́n pín ọtí àti oúnjẹ nítorí àwọn tí ó wá bá wọn ṣe àjọyọ̀ yóò jẹ nígbà tí Àkànní wí pé; Kí jíjẹ àti mímu tó bẹ̀rẹ̀ ẹ jẹ́ kí ń fi Àjàní àti olólùfẹ́ rẹ̀ hàn yín a sá à pàdé lóde kále mọ̀ wọ́n dunjúdunjú oe ÀṢÀ ÌKÍNI Ìkíni jẹ́ àṣà pàtàkì nínú àwọn àṣà Yorùbá ó sì jẹ́ túlààsì fún gbogbo òbí láti kọ́ ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ yìí tèwe tàgbà ló gbọdọ̀ pa àṣà yìí mọ́ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ẹni tí kò kí ni kú ilé ó pàdánù káàbọ̀ èyí ṣe àfihàn pé àṣà ìkíni ní ètò àti pé a kì í fi àgbà tàbí ọjọ́ orí rẹ̀ ènìyàn jẹ níbi ètò ìkíni Ohunkóhun tí Yorùbá ń ṣe ni wọ́n ti máa ń kí ènìyàn bí àpẹẹrẹ ẹni tí ó bímọ Ẹ kú ọwọ́ lómi Òǹkọ̀wé ṣe àmúlò àṣà yìí níbi tí Àkànkẹ́ àti Èébúdọlà ti lọ sí ọ̀dọ̀ Adífáṣẹ Nígbà tí wọ́n fẹ́ wọlé Àkànkẹ́ wí báyìí; Àkànkẹ́ Àbọrúbọyè o Adífáṣẹ Ọ̀rúnmìlà á gbè ọ́ Ní ìgúnlẹ̀ a lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé Olú Owólabí faramọ́ ìgbélárugẹ àṣà Yorùbá lọ́kànòjọ̀kan Tí a bá ka ìwé yìí dáadáa a lè tibẹ̀ mọ onírúurú àṣà tí Yorùbá káràmásìkí àti àwọn tí wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lù Ní òpin gbogbo rẹ̀ òǹkọ̀wé fi yé wa pé títẹ̀lé àṣà àwùjọ kan ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè àwùjọ bẹ́ẹ̀ Lóòótọ́ àṣà máa ń gbèrú ṣùgbọ́n síbẹ̀ òǹkọ̀wé kò gbà pé ó yẹ kí ọ̀làjú gba àṣà wa lọ́wọ́ wa Bí àpẹẹrẹ Dúrójayé tí a rò pé ó yẹ kí ó jẹ́ bàbá fún Àjàní ló tún ń fi ọ̀bẹ ẹ̀yìn jẹ ẹ́ níṣu nípa níní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Àríkẹ́ ìyàwó Àjàní ṣùgbọ́n ohun tó dùn mọ́ ni ni pé òwe Yorùbá kan sọ pé ẹlẹ́sẹ̀ kan kì í yóò lọ láì jìyà Dúrójayé àti àwọn bí i tirẹ̀ tí ó fẹ́ kọ etí ikún sí ìmúṣẹ́ àṣà Yorùbá padà káàbámọ̀ nígbẹ̀yìn ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ ÌFÁÀRÀ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bí ọkọ̀ bá ròkun rọ̀ṣà a fi àbọ̀ sí èbúté Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tó ní ìbẹ̀rẹ̀ tí kì í ní òpin Ní orí karùnún iṣẹ́ yìí a jábọ̀ gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe láti orí kìíní títí dé kẹ́rin A sọ àbọ̀ ìwádìí ní ṣókí àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí lẹ́yìn èyí a dámọ̀ràn fún olùwádìí ọjọ́ iwájú a sì ṣe ìkádìí gbogbo rẹ̀ ÌSỌNÍṢÓKÍ ÀBỌ̀ ÌWÁDÌÍ Nínú iṣẹ́ yìí ohun tí a gbéyẹ̀wò ni ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà tí Olú Owólabí kọ Lẹ́yìn tí a ti ṣe ìwádìí wa a rí àrídájú pé àwọn àṣà Yorùbá tí òǹkọ̀wé bu ẹnu àtẹ́ lù ń fẹ́ àtúnṣe Lára irú ìwà ìbàjẹ́ tàbí àṣà tí òǹkọ̀wé bu ẹnu àtẹ́ lù ni bíbá ìyàwó ọmọ ẹ̀gbọ́n ẹni lò pọ̀ fífi èrú gba ìbùkún Bákan náà iṣẹ́ ìwádìí yìí tún jẹ́ kí a mọ oríṣìí àṣà tó wà Àti pé òǹkọ̀wé Yorùbá kò le kọ ìwé fún àwùjọ Yorùbá láì fi ti ọ̀rọ̀ àṣà ṣe Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé nínú ìwé kíkọ a gbọdọ̀ rántí pé àṣà àwùjọ kan ló sábàá máa ń sọ bí ìgbéayé àwùjọ kan yóò ṣe rí Yàtọ̀ sí èyí ìwádìí yìí tún jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún wà pé kò sí ẹni tí òfin kò le mú Bí àpẹẹrẹ Dúrójayé tí ó lọ bá ìyàwó ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lò pọ̀ A rí i wí pé ìdájọ́ òdodo ni ó rí gbà adájọ́ àgbà kò ṣe ojúsàájú Ní ìgúnlẹ̀ ó hàn kedere pé òǹkọ̀wé gbé àṣà Yorùbá lárugẹ ó sì bu ẹnu àtẹ lu ìwà tó bá ti lòdì sí èyí tí àṣà àwùjọ wa gbà láàyè Òǹkọ̀wé tún fi hàn wá irú wàhálà tó máa ń wà nínú ètò ogún pínpín A rí àpẹẹrẹ Dúrójayé tí ó jẹ ogún ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀ tí ó sì tún ń bá ìyàwó ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lò pọ̀ Ní èyí tí ó lòdì sí àṣà Yorùbá Òǹkọ̀wé bu ẹnu àtẹ́ lu ìlòdìsí àṣà yìí nítorí pé kò le mú ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè bá àwùjọ ÀMÚYẸ ÀTI ÀLÉÉBÙ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Onírúurú ni àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí yìí Lára irú àwọn àmúyẹ bẹ́ẹ̀ nìwọ̀nyí àkọ́kọ́ ni pé iṣẹ́ ìwádìí yìí mú kí ìmọ̀ wa gbòòrò sí i lórí àṣà àwùjọ wa pàápàá jùlọ àwọn àṣà tí òǹkọ̀wé tọ́ka sí Síwájú sí i iṣẹ́ yìí tún sí ojú wa sí pé àparò kan kò ga ju ọ̀kan lọ pàápàá jùlọ lábẹ́ òfin èyí ni pé bákan náà ni gbogbo ènìyàn rí lábẹ́ òfin Ẹni tí ó bá sì sẹ̀ ó di dandan kí irú ẹní bẹ́ẹ̀ ó jìyà ohun tí ó ṣe Àmúyẹ tí a tún rí ni pé Àjàní jẹ́ ẹní tó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí tí a ba wo bí Jẹ́nrìogbé ṣe ń pàrọwà sí i láti jà fún ogún bàbá rẹ̀ kí wọ́n máa fi ọwọ́ ọlá gbá a lójú a rí i pé Àjàní kò bá a jiyàn kò sì tìtorí rẹ̀ sọ̀rọ̀ òdì sí Dúrójayé Gbogbo ohun tí Dúrójayé bá ti ṣe ó fi ara mọ́ ọn Ara àléébù òǹkọ̀wé ni pé a kò rí wí pé wọ́n bá Àríkẹ́ wí fún ohun tí ó ṣe Ọkọ rẹ̀ gan an kò sọ pé ohun tí ó ṣe kò dára kò sì bá a wí Yorùbá sọ pé ẹlẹ́sẹ̀ kan kò ní lọ láìjìyà Èyí kò rí bẹ́ẹ̀ fún Àríkẹ́ tó ṣe àgbèrè pẹ̀lú bàbá ọkọ rẹ̀ Kò sì yẹ kí èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ó tako ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa èrè ẹ̀sẹ̀ ÌMỌ̀RÀN FÚN ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Ìmọ̀ràn wa àkọ́kọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá pé kí wọn gbìyànjú láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìwé eréonítàn Yorùbá tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dórí àtẹ báyìí Èyí yóò jẹ́ kí a tún mọ ìmọ̀ràn tí àwọn náà ń mú wá fún ìdàgbàsókè àwùjọ Síwájú sí i kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú múra sí ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá dáadáa pàápàá jùlọ ìwé eréonítàn Yorùbá nítorí iṣẹ́ tó wà lórí ẹ̀ka lítíréṣọ̀ yìí kéré púpọ̀ a sì nílò láti wá ìmọ̀ kún àwọn ìmọ̀ yìí Lákòótán à ń rọ àwọn òǹkàwé láti máa fi ara balẹ̀ ka àwọn ìwé lítíréṣọ̀ pẹ̀lú èrò láti rí kọjá adùn ìwé náà nítorí kókó tí òǹkọ̀wé fi ìwé rẹ̀ gbé jáde ni ó ṣe pàtàkì jùlọ ÌKÁDÌÍ Kò sí ohun tó ní ìbẹ̀rẹ̀ tí kò ní òpin Nínú iṣẹ́ àkànṣe yìí a ti gbìyànjú láti wo àwọn àṣà Yorùbá àti àwọn àṣà tí òǹkọ̀wé gbé lárugẹ pẹ̀lú èyí tí ó bu ẹnu àtẹ́ lù A gbàgbọ́ pé ẹni tí ó bá ní àǹfààní láti ka iṣẹ́ yìí yóò rí ẹ̀kọ́ kan tàbí òmíràn kọ nínú rẹ̀ èyí tí yóò sì ṣe àwùjọ àti gbogbo wa ní àǹfààní A tún ṣe àtúpalẹ̀ kíkún lórí ìwé eréonítàn Àgbà Tí Ń Yọ́lẹ̀ Dà nípa fífi tíọ́rì àṣà ìbílẹ̀ lítíréṣọ̀ wo ìwé náà A rí wí pé òǹkọ̀wé faramọ́ ìgbélárugẹ àṣà Yorùbá ó jẹ́ kí a gbàgbọ́ pé àṣà le mú ìdàgbàsókè bá àwùjọ wa ÀKÓJỌ ORÚKỌ ÌWÉ Abímbọ́lá W Ìjìnlẹ̀ Ohùn Adéoyè Àṣà àti Ìṣe Yorùbá Ìbàdàn Adéyẹmí Tíọ́rì Lítíréṣọ̀ ní Èdè Yorùbá Ìjẹ̀bú Òde Sebiotimọ Ale àti Ògúnlọlá O Ìwé Ọgbọ́n Ìkọ́ni ní Èdè Yorùbá Ìlọrin Bámgbóṣé Yorùbá Dáramọ́lá àti Jẹ́jẹ́ A Àwọn Àṣà àti Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá Ìbàdàn Oníbọnòjé Dáramọ́láÌgbéyàwó nínú Ọlájubù O Ìwé Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá Ìbàdàn Ògúnṣínà Ìdìde àti Ìdàgbàsókè Lítíréṣọ̀ Àpilẹ̀kọ nínú Àjàyí Ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá Ẹ̀dáÈdè Lítíréṣọ̀ àti Àṣà Sebiotimọ Ọlátúnjí Oyerinde Àkójọpọ̀ Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá Ọ̀yọ́ ÀGBÉYẸ̀WÒ ÀWỌN ÀṢÀYÀN ÈTÒ YORÙBÁ LÓRÍ RÉDÍÒ ÌPÍNLẸ̀ ÀJÀYÍ TÈMITỌ́PẸ́ APÁ KAN IṢẸ́ ÀṢEKÁGBÁ FÚN Ẹ̀KỌ́ ÀKÀGBOYÈ NÍNÚ ÌMỌ̀ ÌPÌLẸ̀ Ẹ̀DÁ Bii Eè NÍNÚ ÈDÈ YORÙBÁ NÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ YUNIFÁSÍTÌ ÌLỌRIN ÌLỌRIN NÀÌJÍRÍÀ OṢÙ IGBE ỌDÚN ÌFỌWỌ́SÍ Iṣẹ́ àkànṣe yìí ni a ti kà tí a sì rí i pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè àti Èdè Nàìjíríà Yunifásítì Ìlọrin Ìlọrin Ọ̀GBẸ́NI ÒKÈWÁNDÉ ỌJỌ́ ALÁBÒÓJÚTÓ OLÙYẸ̀WÒ ÌTA ỌJỌ́ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N ỌJỌ́ OLÓRÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁ ÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ÌFISỌRÍ Mo fi iṣẹ́ àṣekágbá yìí sọrí bàbá mi Olúwọlé Olúṣẹ́gun Àjàyí àti ìyá mi Modúpẹ́ Àjàyí ÌDÚPẸ́ Orin Nígbà tí mo rò ó Iṣẹ́ ìyanu rẹ láyé mi Mo rí pé ó ga Mo rí pé ó ga Mo rí pé ó ga púpọ̀ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bọ́mọdé bá dúpẹ́ oore àná yóò rí òmíràn gbà Ọpẹ́ mi kọ́kọ́ lọ sọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá mi ẹni tí ó mú kí ń wà láyé ayi láàyè títí di ọjọ́ òní tí ó sì tún tì mi lẹ́yìn láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ẹ̀kọ́ yìí Ọlọ́run ó ṣeun lọ́pọ̀lọpọ̀ Bákan náà mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́Èdè Yorùbá ti Yunifásítì Ìlọrin fún ààyè tí wọ́n fi gbàmí láti kọ́ ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá ní abẹ́ àkóṣo wọn Ọpẹ́ mi tún lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gbẹ́ni Òkèwándé tí wọ́n jẹ́ alábòojútó iṣẹ́ àṣekágbá yìí iṣẹ́ ti yín náà kò ní bàjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ti yín náà yóò máa bá aláàánú pàdé Olúwa yóò tọ́jú nǹkan ìní yín tí ó ń mí àti èyí tí kò mí Àmín Mo tún fi àsìkò yìí dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀gá mi lápapọ̀ tí wọ́n kò jẹ́ kí ó hun mí láti ìbẹ̀rẹ̀ tiit dé òpin ẹ̀kọ́ yìí iṣẹ́ yín kò ní dàṣetì ọgbọ́n àti ìmọ̀ yín kò ní díbàjẹ́ lọ́lá Olódùmarè Ń kò ní ṣàì dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ mi pàtàkì aládúrótì mi Onímọ̀ Ẹ̀rọ fún gbogbo ipa tí wọ́n kó láti máa mú mi káàárẹ̀ ọkàn pé àforítì ló ni gbogbo Ẹ ṣeun púpọ̀ gbogbo èròǹgbà ọkàn yín ni Olódùmarè yóò mú wá símúsẹ Yinniyinni kẹ́ni ó ṣe òmíràn ọpẹ́ mi kò ì tan láì dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyáàfin Nímọ́tà Olú Àjàyí tí iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ fún ìgbòkègbodò wọn láti rí i pé iṣẹ́ yìí kẹ́ṣẹ́ járí Ọlọ́run ọba yóò máa ràn yín lọ́wọ́ Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀gbọ́n ni Arákùnrin Ọláyẹmí Àjàyí fún àtìlẹ́yìn wọn Olúwa yóò ṣe gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ti yín ní àsepé Ọpẹ́ mi tún lọ sí ọ̀dọ̀ arábìnrin Ọlánrewájú Àjàyí àti arábìnrin Ọmọdiwúrà Àjàyí tí wọ́n jẹ́ àbúrò mi fún gbogbo àtìlẹ́yìn wọn láti rí i pé mo ṣe àṣeyọrí àti ẹ̀gbọ́n mi pàtàkì arákùnrin Sóìpé Ọládipúpọ̀ láti rí i pé mo ṣe àṣeyọrí iṣẹ́ yìí ẹ ò ní tí ẹ ò ní rá ẹ ò ní díbàjẹ́ ẹ ò ní kú sójú ọ̀nà bí èéfín Ní àkótán kò ní ṣàì dúpẹ́ lọ́wọ́ arákùnrin Daodu fún ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ mi; Búsàrí Fọláyẹmí Adéríbigbé Olúwatósìn Onífádé Bùkọ́lá Dàda Olúwasèyí Àlàbí Kẹ́hìndé Adénẹ́kàn Adéṣọlá Olówólayémọ̀ Olúwatósìn fún ìmọ̀ràn àti àtìlẹ́yìn wọn sí mi Olùwà yóò jẹ́ kí á fi ẹ̀kọ́ yìí ṣe rere láyé lágbára ọ̀gá ògo àmín ÀṢAMỌ̀ Èròǹgbà iṣẹ́ àkànṣe yìí ni ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àṣàyàn ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé a kò lè ya omi kúrò lára aró bẹ́ẹ̀ ni a kò lè ya èdè kúrò lára iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Èdè ni ohun àmúṣagbára wọn yálà lórí rédíò tàbí tẹlifísàn Iṣẹ́ àkànṣe yìí tí tìfuntẹ̀dọ̀ akitiyan àwọn iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ nínú ṣíṣe àmúlò èdè abínibí Yorùbá nínú àwọn ètò wọn Onírúurú àwọn nǹkan ni iṣẹ́ àkànṣe yìí fúnka mọ́ nípa iléiṣẹ́ rédíò tí ó jẹ́ ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ fún iṣẹ́ àkànṣe yìí lára irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni bí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láyé àtijọ́ ṣe máa ń wáyé ṣáájú ṣíṣe àmúlò rédíò àti tẹlifísàn àti ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lóde òní Bí ojúmọ́ ṣe ń mọ́ ni ohun ọ̀tun ń wọlé wá sí àwùjọ wa Ìdí nìyí tí a fi gbọdọ̀ wo ìbẹ̀rẹ̀ ìdìde àti ìdàgbàsókè iṣẹ́ ìròyìn ní ilẹ̀ Nàìjíríà Bákan náà bí a ṣe mọ̀ wí pé orí àwọn àṣàyàn ètò Yorùbá ni iṣẹ́ àkànṣe yìí dálé èyí ló fà á tí a fi ṣe àgbéyẹ̀wò ètò Yorùbá iléiṣẹ́ rédíò yìí láti mọ̀ bóyá mùṣè múṣè wọn dá múṣémúṣé nínú ìlò èdè abínibí wa Onírúurú ọgbọ́n ìwádìí ni a ṣe àmúlò nínú iṣẹ́ yìí lára wọn ni; lílọ sí iyàrá ìkóòwé pamọ́ sí lílọ sí ọ̀dọ̀ abẹ́nàìmọ̀ ìmọ̀ ṣíṣe ìwádìí lórí káyélujára àti dídarapọ̀ mọ́ àwọn akópa Ni ìgúnlẹ̀ a fẹ́ kí iṣẹ́ àkànṣe yìí jẹ́ kí àwọn iléiṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ wa mọ̀ wí pé tẹnintẹni tèkísà ń tààtàn kí ṣíṣe àmúlò èdè Yorùbá lórí rédíò àti tẹlifísàn tún gbòòrò ju èyí lọ ÀTẸ ÀKÓÓNÚ Àkọlé Ìfọwọ́sí Ìfisọrí Ìdúpẹ́ Àṣamọ̀ Ìtọ̀ka olóríjorí ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Ìfáàrà Èrèdí iṣẹ́ ìwádìí Ibi tí ìwádìí gbòròò dé Ọgbọ́n ìwádìí Àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí yìí Ètò ìwádìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN Ìfáàrà Aáyan ọ̀mọ̀ràn lórí èdè Ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ nílẹ̀ Yorùbá Rédíò bí ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ Ìdìde àti ìdàgbàsókè iléiṣẹ́ rédíò ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà Tíọ́rì ìṣàmúlò Tíọ́rì ìfojú ìmọ̀ ìbágbépọ̀ àwùjọ ORÍ KẸ́TA ÀGBÉYẸ̀WÒ ÀṢÀYÀN ÈTÒ ILÉIṢẸ́ RÉDÍÒ ÌPÍNLẸ̀ Ìfáàrà Ìdìde àti ìdàgbàsókè iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ Àwùjọ tí iléiṣẹ́ rédíò ìjọba ìpínlẹ̀ wà Ojúṣe iléiṣẹ́ rédíò ìjọba ìpínlẹ̀ Ètò Yorùbá nílé eṣẹ́ rédíò Àgbékalẹ̀ àwọn ètò orí rédíò ORÍ KẸ́RIN ÈTÒ YORÙBÁ LÓRÍ RÉDÍÒ ÌPÍNLẸ̀ Ìfáàrà Àlàkalẹ̀ àwọn ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ipa àti ìwúlò ètò Yorùbá Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣòro tí ètò Yorùbá ń kojú lórí rédíò ìpínlẹ̀ Lámèyítọ́ lórí àwọn ètò Yorùbá ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ Ìfáàrà Ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí yìí Àmúyẹ àti àléébù ìwádìí Ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú Ìkádìí Àkójọ orúkọ ìwé ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌFÁÀRÀ Ohun tó jẹ wá lógún nínú iṣẹ́ àkànṣe yìí ni iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ ṣùgbọ́n a gbọdọ̀ mẹ́nuba ohun tí rédíò jẹ́ Ní àwùjọ Yorùbá ní ayé àtijọ́ rédíò ni a mọ̀ sí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì Nígbà náà bí olùgbọ́ bá ní ìbéèrè láti bi olóòtú tàbí atọ́kùn ètò kì í sí àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀ Àìsí àǹfààní láti dá sí ètò orí rédíò ló sọ ọ́ di asọ̀rọ̀mágbèsì Lóde òní rédíò ti ń gba èsì Nínú gbogbo ẹ̀rọ tí à ń lò fún ìròyìn ayélujára rédíò ni ó jẹ́ èyí tí owó rẹ̀ kò pọ̀ jù Oríṣìíríṣìí ètò ni a lè gbádùn lórí rédíò Bí ètò abẹ́lé ti wà bẹ́ẹ̀ ni ètò aládàáni wà Bí a ti ń ní ètò tó fara mọ́ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà ni a ní àwọn tó fara mọ́ àṣà àwọn aláwọ̀ funfun Yorùbá ní kò sí bí a ó ṣe perí ajá tí a kò ní perí ìkòkò tí a fi sè é Bẹ́ẹ̀ ni odò kì í sàn kí ó máa ní orísun Ohun tí à ń sọ ni pé kò sí bí a ṣe lè sọ̀rọ̀ rédíò tí a kò ní mẹ́nuba ìdìde rédíò ní ilẹ̀ Yorùbá lápapọ̀ Ohun tí ó ṣe pàtàkì tí a máa ń lò lórí rédíò ni èdè Èdè ni à ń lò láti gbé èrò jáde èdè ni à ń lò fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀ èdè ni à ń fi ń polówó ọjà èdè ni à fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ èdè ni a fi ń kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ Ní ìgúnlẹ̀ ohun tí ó jẹ wá lógún jù nínú iṣẹ́ àkànṣe yìí ni rédíò tí a ó sì mẹ́nuba iléiṣẹ́ rédíò ti ìpínlẹ̀ láti lè tán ìmọ́lẹ̀ sí àǹfààní ìwúlò àti èròǹgbà wọn láti dá iléiṣẹ́ yìí sílẹ̀ ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bí kò bá sí ohun tó ṣẹ́ ẹ̀sẹ́ kì í ṣe lásán bí kò bá nídìí obìnrin kì í jẹ́ kúmólú Èyí túmọ̀ sí wí pé kí òǹkọ̀wé tàbí aṣafọ̀ tó lè mú gègé àrà rẹ̀ láti kọ ìtàn tàbí eré kan ó gbọdọ̀ nií ohun tó gún un ní kẹ́ṣẹ́ inú tàbí tí ó jẹ ẹ́ lọ́kàn Èyí ni mo fi gbìyànjú láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àṣàyàn ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú iṣẹ́ ni a ti rí yálà lórí ìkóròyìnjọ ìlòèdè ọgbọ́n ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí rédíò ìpínlẹ̀ Lára wọn ni a ti rí Ayọ̀délé Babatúndé Ète iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àṣàyàn ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ Kókó pàtàkì tí ó gún mi ní kẹ́ṣẹ́ inú gẹ́gẹ́ bí aṣèwádìí ni láti ṣe àfihàn àṣàyàn àwọn ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ nítorí gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé onírúurú èdè ni wọ́n ń sọ ní ìpínlẹ̀ ṣùgbọ́n ètò Yorùbá ni ó jẹ wá lógún Láti mọ àkókò tí wọ́n ń lò fún àwọn ètò Yorùbá ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àti ní ọ̀sẹ̀ lápapọ̀ àti láti mọ ipa àti ìwúlò àwọn ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ ní àwùjọ yìí IBI Tí ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ Iṣẹ́ yìí yóò ṣe àgbéyẹ̀wò ìdìde àti ìdàgbàsókè rédíò A ó mẹ́nuba ìdìde àti ìdàgbàsókè iléiṣẹ́ rédíò nílẹ̀ Nàìjíríà àti ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ Ní pàtàkì a ó sọ̀rọ̀ lórí iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ ìdìde àti ìdàgbàsókè rẹ̀ àwọn ètò Yorùbá àti ìpínsísọ̀rí àwọn ètò lédè Yorùbá A ó ṣe àmúlò tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì tí a mọ̀ sí tíọ́rì ìmọ̀ ìbáraẹnigbépọ̀ láwùjọ láti ṣe àtúpalẹ̀ àwọn ètò lédè Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ A ó wo àwùjọ tí iléiṣẹ́ yìí wà ìṣòro tí èdè Yorùbá ń dojú kọ àti ipa ìjọba ìpínlẹ̀ lórí iléiṣẹ́ yìí láti borí ìṣòro yìí Bákan náà a ó wo àwọn ètò Yorùbá láti bí ọdún mẹ́ta sẹ́yìn àkókò tí wọ́n ń lò fún àwọn ètò yìí àti ohun tí ó fa ìlò àkókò tí wọ́n ń lò fún ètò Yorùbá A ó sọ àkójọpọ̀ àbọ̀ ìwádìí àmúyẹ àti àléébù ìwádìí ìwúlò ìwádìí fún àwùjọ akẹ́kọ̀ọ́ àti ìmọ̀ràn fún ọjọ́ iwájú ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ Oríṣìíríṣìí ọgbọ́n ni a lè ṣàmúlò Èyí tí a ó ṣàmúlò ni ọgbọ́n ìwádìí aṣàkíyèsí ọgbọ́n ìwádìí ìwòran ọgbọ́n ìwádìí lílọ sí yàrá ìkówépamọ́sí àti ọgbọ́n ìwádìí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Ọgbọ́n ìwádìí aṣàkíyèsí akópa yìí jẹ́ ọ̀nà ìwádìí tó ní í ṣe pẹ̀lú kí aṣèwádìí lọ sí àárín akópa láti ṣe bí i ọ̀kan lára wọn kí èyí lè fún aṣèwádìí ní àǹfààní àti rí ìwádìí rẹ̀ ṣe Nígbà mìíràn ó ṣe é ṣe kí aṣèwádìí darapọ̀ mọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn akópa kí wọ́n sì máa mọ èròǹgbà rẹ̀ títí tí yóò fi ṣe àtòjọ ìwádìí rẹ̀ Ọgbọ́n ìwádìí lílọ sí yàrí ìkówépamọ́sí yìí náà jẹ́ ọ̀kan lára ọgbọ́n ìwádìí tí aṣèwádìí máa ń lò Yóò wúlò fún iṣẹ́ yìí láti lè jẹ́ kí a mọ onírúurú àwọn onímọ̀ tí ó ti kọ̀wé lórí rédíò Ọgbọ́n ìwádìí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò jẹ́ ọgbọ́n tó jẹ́ mọ́ ṣíṣe ìwádìí ní ọ̀dọ̀ abẹ́nàìmọ̀ láti gbé lọ ṣe ìwádìí nípa irúfẹ́ iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀ Aṣèwádìí yóò gbìyànjú láti fi ọ̀rọ̀ wá abẹ́nàìmọ̀ rẹ̀ lẹ́nu wò láti bèèrè gbogbo ohun tó ṣe pàtàkì fún iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀ Ọgbọ́n ìwádìí lílo ẹ̀rọ ayélujára jẹ́ ọgbọ́n tí aṣèwádìí máa ń lò láti wádìí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára tí yóò sì wúlò fún láti ṣe iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀ Irú àwọn ọgbọ́n yìí ni a lò láti ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀ lórí iṣẹ́ ìwádìí yìí ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ kún ìmọ̀ nípa iléiṣẹ́ rédíò ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà àti ní pàtàkì rédíò ìpínlẹ̀ tí iṣẹ́ yìí dálé Lọ́nà mìíràn yóò tún jẹ́ kí a mọ àwọn ètò tí wọ́n máa ń fi èdè Yorùbá gbé jáde lórí rédíò àti ipa irú àwọn ètò bẹ́ẹ̀ láwùjọ Àǹfààní mìíràn ni pé a ní àǹfààní láti rí ẹwà tí ó wà nínú èdè Yorùbá nínú àwọn ètò tí ó bá jẹ mọ́ lílo ohùn ẹnu Yorùbá bí i; ewì alohùn yóò jẹ́ kí àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ọgbọ́n àtinúdá ewì alohùn jáde láti gbé èdè Yorùbá lárugẹ láti máa jẹ́ kí èdè Yorùbá ó kú ÈTÒ ÌWÁDÌÍ Orí kìíní tó jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò jẹ́ èrèdí iṣẹ́ ìwádìí ibi tí ìwádìí yìí gbòòrò dé ọgbọ́n ìwádìí àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí àti ètò ìwádìí Nínú orí kejì tó jẹ́ aáyan ọ̀mọ̀ràn yóò jẹ́ aáyan ọ̀mọ̀ràn lórí èdè ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ nílẹ̀ Yorùbá rédíò bí ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ìdìde àti ìdàgbàsókè rédíò ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà àti lílo tíọ́rì ìmọ̀ ìbágbépọ̀ àwùjọ wo ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ Orí kẹ́ta yóò ṣàgbéyẹ̀wò àṣàyàn ètò iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ Ìdìde àti ìdàgbàsókè iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ àwùjọ tí iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ wà ojúṣe iléiṣẹ́ rédíò ìjọba ìpínlẹ̀ àti àgbékalẹ̀ àwọn ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ Orí kẹ́rin yóò dálé àmúlò tíọ́rì ìmọ̀ ìbáraẹnigbépọ̀ àwùjọ láti wo ọ̀kanòjọ̀kan àwọn ètò tí iléiṣẹ́ yìí ń dágbálé fáráàlú ipa tí èdè Yorùbá ń kó nínú ètò ọrọ̀ajé amúlùúdùn ìbágbépọ̀ àwùjọ ìgbélárugẹ ẹ̀sìn àṣà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Orí karùnún ni ó jẹ́ àgbálọgbábọ̀ Níbi a ó sọ ní ṣókí àbọ̀ ìwádìí àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí àti ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN ÌFÁÀRÀ Ìgbà laṣọ ìgbà lẹ̀wù Ìgbà ni òdèèré ikókò nílù Ìlọrin Ohun gbogbo tí ó wà nínú ilé ayé ni ó ní àkókò tàbí ìgbà tirẹ̀ Ní ayé àtijọ́ onírúurú ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ni ó wà bí i alóre alamí ìlù lílù agogo lílù fèrè fífọn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lóde òní nǹkan ti yípadà A ti ń lo ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tó yàtọ̀ sí ti ayé àtijọ́ Àwọn ọ̀nà tí à ń gbà fi ìròyìn tó àwọn ènìyàn létí láyé àtijọ́ kò ju àdúgbò tàbí agbègbè tí a ti gbé ìròyìn náà kalẹ̀ lọ Lóde òní àǹfààní ìròyìn ṣíṣe ti wà lọ́nà ayélujára àti ní agbègbè lápapọ̀ Kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn ni ó ní ìmọ̀ ìròyìn ṣíṣe ayélujára yìí nítorí àìmọ̀ọ́nkọ mọ̀ọ́nkà àwọn mìíràn Àwọn mìíràn kò sì ka ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ayélujára yìí kún rárá àwọn mìíràn wà tí ó jẹ́ pé ọ̀dá owó ni ó dá wọn tí wọn kò sì le ra àwọn ohun èlò tí wọn yóò máa lò fún irú ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ yìí A lè sọ pé àwọn mìíràn kò ní ìmọ̀ nípa àwọn oníṣẹ́ ìròyìn ìmọ̀ tásẹ́rẹ́ sì ni àwọn mìíràn ní ohun tó ṣokùnfà èyí ni pé púpọ̀ ìwé ìròyìn ni wọ́n kọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì tí kò sí ní èdè Yorùbá wọn a sì máa tà òmíràn ní owó gọbọi Ní àwùjọ Yorùbá èdè kó ipa pàtàkì nínú ohun yòówù tí ènìyàn bá ń ṣe Èyí fi hàn pé ipa kékeré kọ́ ni èdè Yorùbá ń kó nínú iṣẹ́ ìròyìn A kò sì le fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àmúlò èdè nínú iṣẹ́ ìròyìn Èdè jẹ́ ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láàárín ọmọnìyàn àwọn akọ̀wé ìwé ìròyìn gbọdọ̀ mọ àpadé àti àludé èdè Yorùbá kí wọ́n lè kẹ́ṣẹ́ járí nínú iṣẹ́ ìròyìn wọn Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí a ó ṣàmúlò tíọ́rì ìmọ̀ ìbáraẹnigbépọ̀ àwùjọ Tíọ́rì yìí ni a ó fi ṣe àtúpalẹ̀ àwọn ètò Yorùbá ní orí rédíò ìpínlẹ̀ Tíọ́rì yìí ni a ó fi wò ó bóyá àwọn ètò tí wọ́n ń gbé jáde lédè Yorùbá wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ènìyàn àwùjọ bóyá àkókò tí wọ́n fún àwọn ètò kọ̀ọ̀kan wà ní ìbámu pẹ̀lú iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè Yorùbá ní àwùjọ náà Tíọ́rì yìí ni a ó fi wo ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ènìyàn àwùjọ a ó fi wò ó bóyá wọ́n pín àkókò fún àwọn olówó àti mẹ̀kúnnù bákan náà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ Tíọ́rì yìí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú èdè tí àwọn akọ̀rọ̀yìn ń lò fún àwọn ènìyàn láwùjọ bí i àwọn olóṣèlú àwọn olówó mẹ̀kúnnù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN LÓRÍ ÈDÈ Ọ̀kan nínú ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ láàárín àwọn ọmọ adáríhurun ni èdè ọ̀rọ̀ sísọ àti bíbá araẹnisọ̀rọ̀ Èdè ni ohun tí ó lágbára jùlọ tí a fi ń báraẹnísọ̀rọ̀ Nínú Bíbélì ni a ti kà á pé èdè kan ni gbogbo ayé fi ń bára wọn sọ̀rọ̀ títí di ìgbà tí wọ́n panupọ̀ pé àwọn fẹ́ kan àkàsọ̀ tí yóò dé ọ̀run láti lè bá Ẹlẹ́dàá sọ̀rọ̀ tí Ẹlẹ́dàá sì da èdè wọn rú ní Gẹ́nẹ́sísì orí kọkànlá ẹsẹ kìíní dé ìparí láti ìgbà náà ni onírúurú ẹ̀dá náà ti wọnú ayé kò sì sí ẹ̀ka ìṣeṣí ẹ̀dá láyé tí èdè kò kópa nínú rẹ̀ Onírúurú onímọ̀ ni ó ti ṣiṣẹ́ lórí ohun tí èdè túmọ̀ sí sọ nípa èdè báyìí Èrò ọkùnrin yìí ni pé Èdè jẹ́ àtòpọ̀ ìró tí a fi ọ̀rọ̀ ẹnu gbé jáde ní ìbámu pẹ̀lú òfin kan èyí tí ó mú kí ohun tí aṣafọ̀ ń sọ yé olùgbọ́ sọ nípa èdè báyìí; Èrò ọkùnrin yìí ni pé; Èdè kì í ṣe ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ nìkan lórí kókó ọ̀rọ̀ kan tàbí òmíràn Ó tún jẹ́ ohun tí ó mú kí àwọn ènìyàn ní àjọsepọ̀ láàárín ara wọn Ìwé atúmọ̀ èdè Èyí túmọ̀ sí pé; Èdè ni ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tó ní ìró tàbí ọ̀rọ̀ tàbí ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí àwọn àwùjọ kan ń lò tàbí iṣẹ́ kan Tí a bá wo gbogbo ìtumọ̀ tí àwọn onímọ̀ fún èdè a rí i pé gbogbo wọn ni ó mẹ́nubà á pé èdè jẹ́ ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ A lè tún fi kún un pé èdè ni ó ń mú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ìdàgbàsókè bá àwa ènìyàn Èdè ṣe pàtàkì ní àwùjọ Yorùbá Èdè yìí sì ni ó ya ènìyàn sọ́tọ̀ sí ẹranko ṣùgbọ́n bí èdè ṣe wúlò tó Yorùbá ní òwúyẹ́ ni ọ̀rọ̀ wọ́n a tún wí pé ẹyin ni ọ̀rọ̀ bí ó bá jábọ́ kò ṣe é kó Èyí ni pé bí a ṣe lè fi èdè tún ti ènìyàn ṣe náà ni a lè fi ba ti ènìyàn jẹ́ Yorùbá máa ń wí pé ẹni bá mọ ọ̀rọ̀ sọ kí ó rántí ẹni mọ̀ ọ́ gbọ́ Ọ̀NÀ ÌBÁRAẸNISỌ̀RỌ̀ NÍLẸ̀ YORÙBÁ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní kí àgbàdo tó dáyé nǹkan kan ni adìyẹ ń jẹ kí ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ayélujára tó dé àwùjọ Yorùbá Ó ní bí àwọn Yorùbá ṣe ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì ń gbà kọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ ilé ó sì ń ní bí wọn ṣe ń fi ìròyìn tó ara wọn létí Bákan náà ó ní bí wọ́n ṣe ń gbádùn ara wọn pẹ̀lú ètò ọlọ́kanọ̀jọ̀kan Yorùbá kò fi ìgbádùn ṣeré rárá lẹ́yìn iṣẹ́ òòjọ́ wọn lára ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà ṣe fàájì tí wọ́n sì ń gbà bára wọn sọ̀rọ̀ ni kí wọ́n fi oríṣìíríṣìí orin dárayá lálẹ́ Olúkoju Nígbà mìíràn àwọn àgbà lè kó àwọn ọmọdé jọ lálẹ́ kí wọ́n pa àlọ́ Bí ó bá sì ṣe ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ni àwọn Yorùbá le fi ayò ẹkẹ tàbí ìjàkadì dárayá Kọ́mọláfẹ́ Bí ẹnìkan bá fẹ́ ṣe ayẹyẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè gbé ikọ̀ dìde láti máa ti ilé dé ilé àti àdúgbò dé àdúgbò láti máa fi ayẹyẹ náà tó àwọn ènìyàn létí Àwọn olólùfẹ́ a máa fi òkúta ṣe ààmì ìbáraẹnisọ̀rọ̀ nípa jíju òkúta sí òrùlé olólùfẹ́ Kọ́mọláfẹ́ Ìròyìn fífi ránṣẹ́ nílẹ̀ Yorùbá ní àtijọ́ le jẹ́ àfẹnusọ tàbí àìfẹnusọ bí i àrokò Nípa ọ̀nà àfẹnusọ àwọn Yorùbá a máa lo àwọn alamí Ọlájubù ní nínú ogun jíjà ipò pàtàkì ni alamí kó nínú àwọn ọmọogun nílẹ̀ Yorùbá Bí ìlú kan bá ń palẹ̀ ogun mọ́ wọ́n á yan àwọn kan tí wọn yóò máa jẹ́ amí fún àwọn olórí ogun Àwọn alamí wọ̀nyí tí ní àmì tí wọn yóò máa ṣe tí àwọn ọmọogun yóò fi mọ̀ pé ogun ti dé ibì kan èyí jẹ́ ọ̀nà kan tí àwọn Yorùbá ń gbà bara wọn sọ̀rọ̀ Ọ̀nà mìíràn tí á mẹ́nubà ni lílo àwọn alóre Ọlájubù Ọlátúnjí Wọ́n mẹ́nuba alóre gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí à ń gbà bára wa sọ̀rọ̀ nílẹ̀ Yorùbá Wọ́n ní àwọn alóre ni ó máa ń wà ní ẹnu ibodè ìlú tí wọ́n máa ń sọ fún ìlú tí Ògún bá tí ń bọ̀ wá sí ìlú Àwọn babańlá wa máa ń kọ́ ilé ìṣọ́ sí ẹnu bodè sí gbogbo ibi tí ọ̀nà gbà wọ ìlú Ibí yìí ni a máa ń fi àwọn alóre sí Iṣẹ́ wọn ni láti máa sin àwọn arìnrìnàjò wọ ìlú láti wádìí lẹ́nu wọn bí wọ́n wá tajà ni tàbí aámí ni wọ́n Bí alóre bá rí ọ̀tá tí ó ń bọ̀ wá ja ìlú láti òkèèrè á ta àwọn ìlú lólobó Á ki fèrè rẹ̀ bọnu yóò sì fọn ọ́n Àwọn ọ̀nà mìíràn tí wọ́n tún mẹ́nubà ní ìlù lílù Àwọn Yorùbá a máa fi ìlù bá ara wọn sọ̀rọ̀ tí àyàn bá ti lu ìlù rẹ̀ ẹni tí ó bá mọ ohùn ìlù ni yóò lè túmọ̀ ohun tí àyàn ń sọ Bí ìlù ṣe máa ń dún ènìyàn nínú tí ó jẹ́ ọ̀nà ayọ̀ ni a lè sọ pé ó máa ń ba nǹkan jẹ́ RÉDÍÒ BÍ Ọ̀NÀ ÌBÁRAẸNISỌ̀RỌ̀ Ète àti lè bá ara ẹni sọ̀rọ̀ láàárín olùsọ̀rọ̀ tó jìnnà ló ṣe okùnfà àti wáyé rédíò àti tẹlifísàn Àti bára ẹní sọ̀rọ̀ ní itòsí kì í ṣe ohun tó ṣòro ṣùgbọ́n nígbà tí olùgbọ́ àti olùsọ bá jìnnà sí ara wọn ni wàhálà Ọ̀nà láti kojú ìṣòro yìí ló mú kí àwọn onímọ̀ bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lọ́nà jínjìn réré Àwọn ohun mìíràn ni ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó fi ààyè sílẹ̀ fún onírúurú iṣẹ́ ìwádìí nítorí láti ìgbà tí ẹ̀kọ́ ti bẹ̀rẹ̀ ni ìwádìí ti ń tẹ̀síwàjú kò sì dópin títí di òní Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí a ṣe lórí ẹ̀rọ ayélujára ó fi hàn wá pé kì í ṣe onímọ̀ kan ni ó ṣiṣẹ́ lórí àtiwáyé rédíò Dáramọ́lá fún rédíò ní oríkì yìí Ohun tí Dáramọ́lá ń sọ ni pé Rédíò ni ohun èlò ìró pàtàkì tí à ń lò yálà láti sọ nǹkan fún àwọn olùgbọ́ ní pàtàkì ohun tó ń lọ nílé tàbí ní àgbáyé láti yí wọn lọ́kàn padà láti rà tàbí dán ohun tí à ń tà tàbí pèṣè wò kí wọ́n túbọ̀ máa gbọ́ ilé iṣẹ́ náà tàbí láti dá wọn lára yá Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a máa ń gbé jáde lórí rédíò nípasẹ̀ ìró Lára àwọn onímọ̀ tí wọ́n ṣiṣẹ́ lórí àtiwáyé rédíò gẹ́gẹ́ bí ìwádìí lórí ẹ̀rọ ayélujára ni Ó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó pilẹ̀ ọgbọ́n ìfìróránṣẹ́ Ó ṣe ẹ̀rọ kan tí a mọ̀ sí tẹ́lígíráfù oníná mọ̀nàmọ́ná Ìwádìí mìíràn bẹ̀rẹ̀ wọ́n gbìyànjú láti ṣe ẹ̀rọ mìíràn èyí tí kò ní lo wáyà èyí ni a mọ̀ sí èyí tí a mọ̀ sí rédíò Ní ọdún ṣe ìwádìí kan tí ó fi hàn pé ọ̀rọ̀ lágbára láti mi afẹ́fẹ́ àti pé agbára afẹ́fẹ́ tí à ń wí yìí ni òǹfà tí ń fa ìró mọ́ra nínú wéèfù ohun tí ìwádìí yìí fi hàn wá ni pé mágínẹ́ẹ̀tì tí ó le gbé ìró rìn ń bẹ nínú wéèfù Ní ọdún ọkùnrin Itali kan tí ó ń jẹ́ gbìyànjú láti tẹ̀síwàjú nínú ìwádìí yìí Ní ọdún ó bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ sí Ní ó fi àwọn àmì ránṣẹ́ láti bèbè Àtìláńtíìkì àti Àmì yìí rìn tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́ta kìlómítà ṣùgbọ́n èyí tí ó ṣe yìí kò kógo já nítorí kọ́ọ̀dù náà ni ó lò Ìwádìí tẹ̀síwàjú dípò kí wọ́n fi àmì ránṣẹ́ wọ́n fi ohùn ránṣẹ́ ní ọkùnrin kan tí à ń pè ní olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ní Àmẹ́ríkà Ó bẹ̀rẹ̀ ìwádìí kan tó lágbára látàrí àtilè fi eré àti ohùn ránṣẹ́ dípò ohùn lásán Àbájáde ìwádìí náà ni pé ó fi ohùn ènìyàn ránṣẹ́ Ní ọjọ́ kérésì ní ni ó ṣe àṣeyọrí nípa fífi ohùn ènìyàn ránṣẹ́ Ìwádìí yìí ló bí rédíò tí kò ní wáyà tí à ń lò Ìwádìí fi hàn pé Àmẹ́ríkà ló ti bẹ̀rẹ̀ kí ó tó dé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì títí ó fi dé ilẹ̀ Nàìjíríà ÌDÌDE ÀTI ÌDÀGBÀSÓKÈ ILÉIṢẸ́ RÉDÍÒ NÍ ORÍLẸ̀ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ Ó ṣe pàtàkì kí á mọ àsìkò tí iléiṣẹ́ rédíò bẹ̀rẹ̀ ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà sọ pé ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kéjìlá ọdún ni iléiṣẹ́ rédíò bẹ̀rẹ̀ ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà nípasẹ̀ iléiṣẹ́ ìfìwé ránṣẹ́ ti ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bẹ̀rẹ̀ Àwọn ètò orí rédíò tí ń lo afẹ́fẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ alátagbà Ní ọdún yìí kan náà ni ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pa á láṣẹ fún iléiṣẹ́ ìfìwé ránṣẹ́ tí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti ṣe ètò bí wọ́n yóò ṣe máa gbé àwọn ètò iléiṣẹ́ rédíò ìjọba Gẹ̀ẹ́sì dé etígbọ̀ọ́ àwọn ará ìlú ńlá ńlá bí i Èkó Kano àti Ìbàdàn Ìdí nìyí tí a fi sọ pé ọdún ni rédíò bẹ̀rẹ̀ ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà Gẹ́gẹ́ bí ṣe ṣàlàyé iléiṣẹ́ rédíò ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ láti ibi ṣíṣe àtagbà àwọn ètò tí iléiṣẹ́ rédíò tún gbé wá sí etígbọ̀ọ́ àwọn ènìyàn orílẹ̀èdè yìí iléiṣẹ́ ìfìwé ránṣẹ́ Nàìjíríà ní abẹ́ àkóso ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni ó ṣe akitiyan yìí tẹ̀síwàjú pé àbájáde ní oṣù kẹ́jọ ọdún ni ó fa àgbékalẹ̀ iléiṣẹ́ rédíò Nàìjíríà ní ọdún Láàrọ̀ ṣàlàyé pé yàtọ̀ sí ìlú Èkó Ìbàdàn àtio tí ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ wà wọ́n tún dá àwọn mìíràn sílẹ̀ ní àti sọ pé ìjọba dá àwọn iléiṣẹ́ rédíò sílẹ̀ ní àwọn orílẹ̀èdè tí wọ́n ti ń ṣe àkóso pàápàá jùlọ ní àti àwọn ilẹ̀ adúláwọ̀ tí wọ́n ti ṣe àkóso fún àǹfààní ara wọn ni láti lè máa polongo àwọn ètò ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Wọn kò fún àwọn alátakò ní ààyè láti sọ ti ẹnu wọn fún aráyé gbọ́ Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ń lo rédíò láti sọ irọ́ di òótọ́ nípa ọ̀rọ̀ ìṣèlú orílẹ̀ Nàìjíríà èyí sì máa ń fa awuyewuye láàárín àwọn olóṣèlú Iléiṣẹ́ rédíò wà títí di ọdún kí ó tó di àjọ ńlá rédíò ilẹ̀ wa Títí di ọdún ètò rédíò ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni à ń gbọ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà Ètò bí i; ìròyìn ìdárayá àti ìkéde wọ́n ń lo èdè Haúsá Yorùbá àti Ìgbò Àwọn òṣìṣẹ́ yóò gba ohùn sílẹ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì wọn yóò sì túmọ̀ rẹ̀ sí èdè abínibí Ọdún ni èdè Yorùbá ti di àmúlò Ọdún ni iléiṣẹ́ rédíò Nàìjíríà di òmìnira tí wọ́n sì ń ṣe ètò ara wọn Wọ́n yí orúkọ wọn padà kúrò ní sí òun ló sì yípadà sí Rédíò Nàìjíríà Iléiṣẹ́ rédíò ti wá pọ̀ ní ilẹ̀ Nàìjíríà pàápàá nígbà tí epo rọ̀bì dé Lára àwọn iléiṣẹ́ rédíò ní ilẹ̀ Nàìjíríà tí a lè mẹ́nubà nìyí; Rédíò Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ ní Rédíò Àkúrẹ́ bẹ̀rẹ̀ ní Rédíò Ìkẹjà bẹ̀rẹ̀ ní Rédíò Ìbàdàn bẹ̀rẹ̀ ní Rédíò Abẹ́òkúta bẹ̀rẹ̀ ní Rédíò Ìlọrin bẹ̀rẹ̀ ní Rédíò bẹ̀rẹ̀ ní Rédíò Ọ̀yọ́ bẹ̀rẹ̀ ní Rédíò bẹ̀rẹ̀ ní Rédíò Oǹdó bẹ̀rẹ̀ ní Rédíò Ògùn bẹ̀rẹ̀ ní bẹ̀rẹ̀ ní Ó yẹ kí a fi kún pé Nàìjíríà lóde òní ní àwọn rédíò aládàáni lọ́kànòjọ̀kan Ìdásílẹ̀ wọn wáyé nígbà ìjọba Babangida Ó gbé òfin kan kalẹ̀ tó jẹ́ tológun òfin yìí ló ṣe àtìlẹ́yìn fún ìdásílẹ̀ iléiṣẹ́ rédíò aládàáni Láti ìgbà yìí ni a ti ní ilẹ̀iṣẹ́ rédíò aládàáni Lára wọn ni;bẹ̀rẹ̀ ní bẹ̀rẹ̀ ní bẹ̀rẹ̀ ní bẹ̀rẹ̀ ní TÍỌ́RÌ ÌṢÀMÚLÒ ÌṢÀMÚLÒ TÍỌ́RÌ ÌBÁGBÉPỌ̀ ÀWÙJỌ Tíọ́rì tí a ó ṣe àmúlò nínú iṣẹ́ yìí ni tíọ́rì ìbágbépọ̀ àwùjọ tàbí tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì láti ṣe àgbéyẹ̀wò ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ Tíọ́rì yìí ni a ó lò láti wò tàbí mọ̀ bóyá ètò tí à ń gbé sí afẹ́fẹ́ wà ní ìbámu pẹ̀lú ètò tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń lọ lọ́wọ́ ní àwùjọ Yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ kíkún nípa àwọn ènìyàn àwùjọ àti ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú àwùjọ a ó sì mọ ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àwùjọ pàápàá àwọn ènìyàn àwùjọ tí iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ wà Soṣíọ́lọ́jì jẹ́ ọ̀rọ̀ tí onímọ̀ èrò ìjìnlẹ̀ kan tí à ń pè ní Taine ọmọ ilẹ̀ Faranse rọ fúnra rẹ̀ Oníṣẹ́ lámèyítọ́ ni Taine láàárín ọdún gẹ́gẹ́ bí Adéyẹmí Soṣíọ́lọ́jì jẹ́ ọ̀rọ̀ láti inú èdè Látìnì tí a mọ̀ sí tí ó túmọ̀ sí ìṣepọ̀ Bákan náà àwọn Gíríkì pè ní tí ó túmọ̀ sí Sáyẹ́ńsì Sáyẹ́ńsì yìí ni Látìnì ń pè ní to tí ó túmọ̀ sí láti mọ̀ Soṣíọ́lọ́jì jẹ mọ́ gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá jẹ mọ́ ìran ọmọ ènìyàn àti ìbáṣepọ̀ láàárín wọn Ìrírí àwọn ènìyàn láwùjọ ènìyàn àti ìrànmọ́ tí irú ìrírí àti àjọsepọ̀ bẹ́ẹ̀ lè fá bá ẹ̀dá Ajólórí Soṣíọ́lọ́jì ni ènìyàn àwùjọ àti ìbáṣepọ̀ wọn àti ipa tí irú ìbáṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ ní lórí àwùjọ Ohun tí ó jẹ Soṣíọ́lọ́jì lógún jù ni ìgbé ayé ẹ̀dá nínú àwùjọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ àṣà ìwà àti èdè rẹ̀ èyí tí ó jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ẹ̀dá dúró lé Ohun tí ń sọ nípa Soṣíọ́lọ́jì ni èrò tirẹ̀ ni pé àwọn ènìyàn láwùjọ ìwà irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ àti ìdàgbàsókè irú àwùjọ bẹ́ẹ̀ ni à ń pè ní Soṣíọ́lọ́jì Soṣíọ́lọ́jì dá lórí ìwà àwùjọ Ohun tí ń ṣàlàyé ni pé ìwà àwùjọ pọ́ńbélé ni à ń pè ní Soṣíọ́lọ́jì sọ báyìí nípa Soṣíọ́lọ́jì; Soṣíọ́lọ́jì ni Sáyẹ́ńsì tí ó máa ń lépa títúmọ̀ òye nípa ìwà àwùjọ láti ṣàlàyé ìdí ipa ọ̀nà àti èrè irú ìwà bẹ́ẹ̀ Ohun tí ń ṣàlàyé ni pé ọgbọ́n láti fi oríṣìíríṣìí ìwà àwùjọ hàn ohun tí ó fa irú ìwà bẹ́ẹ̀ ní àwùjọ ni à ń pè ní Soṣíọ́lọ́jì sọ nípa Soṣíọ́lọ́jì báyìí; Nígbà kan rí àwọn ènìyàn máa bá wọn ṣe nǹkan pọ̀ Ìmọ̀ nípa ìbáraẹniṣepọ̀ yìí lónírúurú ọ̀nà ni Soṣíọ́lọ́jì Lójú Soṣíọ́lọ́jì gbòòrò ju ìbáṣepọ̀ láàárín àwọn ènìyàn lọ Àríwòye ti ni pé ròǹgbà Soṣíọ́lọ́jì ni láti mọ̀ nípa àwùjọ nípasẹ̀ ìmọ̀ sàyẹ́ńtífíkì Bákan náà ó ṣe àgbékalẹ̀ wíwá ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro fúnra rẹ̀ sí àwọn ìbéèrè báwo láwùjọ ṣe rí? Bawo ni wọ́n ṣe ń ṣe? Ìdí tí àwùjọ fi ń tẹ̀síwàjú? Oríkì yìí gbòòrò ṣùgbọ́n àkíyèsí tí a nílò náà ni pé nínú gbogbo oríkì tí àwọn onímọ̀ fún Soṣíọ́lọ́jì wọn kò yọ àwùjọ ọmọnìyàn sílẹ̀ Ohun tí Soṣíọ́lọ́jì ń fúnka mọ́ náà ni àgbéyẹ̀wò àti àlàyé lórí àwọn ohun tó ń ṣe okùnfà ìlọsíwájú tàbí ìfàsẹ́yìn bá àwùjọ kan Ó tún máa ń ṣe ìwádìí nípa bí àwùjọ ṣe ń yípadà àti ìhà tí àwùjọ kọ sí ètò ọrọ̀ajé ètò ìṣèlú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ àti ipa tí ìhà tí wọ́n kọ sí àwọn ètò yìí ní lórí wọn ORÍ KẸ́TA ÀGBÉYẸ̀WÒ ÀṢÀYÀN ÈTÒ ILÉIṢẸ́ RÉDÍÒ ÌPÍNLẸ̀ IFAARA Onírúurú ọ̀nà tí à ń gbà fi ìròyìn tó àwọn ènìyàn létí láwùjọ ní ayé àtijọ́ kò tayọ àdúgbò tàbí agbègbè tí a ti ń gbé ìròyìn bẹ́ẹ̀ kalẹ̀ Ète àti lè bá ara ẹni sọ̀rọ̀ lọ́nà tó jìnnà ló ṣokùnfà àtiwáyé rédíò àti tẹlifísàn Àwọn ohun mìíràn ni ìmọ̀ Sáyẹ́ńsì tó gún àwọn Òyìnbó ní kẹ́sẹ́ àti lè máa ṣe ìwádìí nǹkan Ètò orí rédíò ní ilẹ̀ Nàìjíríà àti lágbàáyé jẹ́ ọ̀nà tí à fi ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀ láìfi ti ẹ̀yà ìṣèlú àti ẹ̀sìn ṣe Ìyẹn ni pé òjò ni rédíò kò bá ẹnìkan sọ̀tá Ó rọrùn púpọ̀ fún àwọn oníṣẹ́ ìròyìn láti fi èrò ránṣẹ́ lórí rédíò ju iléiṣẹ́ ìròyìn yòókù lọ Ìdásílẹ̀ àwọn ìpínlẹ̀ tuntun tó wáyé lórílẹ̀èdè yìí ní ọdún àti ní ṣíṣẹ̀ntẹ̀lé pẹ̀lú fífàyègba ìdásílẹ̀ rédíò ìjọba àti aládàáni ló mú kí afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí kún fún onírúurú ètò alárinrin Èyí ló sì fún àwọn olùgbọ́ ní àǹfààní láti yan ojúkọ̀ rédíò tó bá wù wọ́n láàyò fún ìgbádùn lórí afẹ́fẹ́ Akọ̀ròyìn tàbí oníṣẹ́ ìròyìn ni orúkọ tí àwọn ènìyàn máa ń sábàá pe àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ rédíò ni kì í ṣe jíjábọ̀ ìròyìn nìkan niṣẹ́ àwọn akọ̀ròyìn ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ fún ní ìtumọ̀ nípa bẹ́ẹ̀ yóò ran àwùjọ lọ́wọ́ láti dá sí ohun tó ń lọ láwùjọ bí i ọrọ̀ajé ẹ̀sìn ìṣèlú Àwọn oníṣẹ́ iléiṣẹ́ rédíò tàbí ìròyìn ni a lè pè ní atọ́nà amọ̀nà alúkoro alóre Àwọn oníṣẹ́ iléiṣẹ́ ìròyìn máa ń ta àwùjọ jí sí ohun tó ń lọ ní àwùjọ Ní abala yìí ni a ó ti wo ìdìde àti ìdàgbàsókè iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ àwùjọ tí iléiṣẹ́ náà wà ètò Yorùbá níléeṣẹ́ rédíò ojúṣe iléiṣẹ́ rédíò ìjọba ìpínlẹ̀ àti àgbékalẹ̀ àwọn ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ ÌDÌDE ÀTI ÌDÀGBÀSÓKÈ ILÉIṢẸ́ RÉDÍÒ ÌPÍNLẸ̀ Ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹ́rin ọdún ìjọba ilẹ̀ Nàìjíríà gbé ìlànà kan kalẹ̀ pé gbogbo iléiṣẹ́ rédíò Nàìjíríà tí ó wà ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ni kí ó di ti ìjọba ìpínlẹ̀ tí wọ́n wà Ìyọ̀ǹda iléiṣẹ́ rédíò Nàìjíríà fún ìpínlẹ̀ ni ọ̀gbẹ́ni tó jẹ́ ọ̀gá rédíò Nàìjíríà ní ìpínlẹ̀ Èkó ṣe ní ọjọ́ karùnún oṣù kẹ́sànán ọdún Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ iléiṣẹ́ rédíò Nàìjíríà tó wà ní ìpínlẹ̀ ni wọ́n fún ní àǹfààní láti dúró tàbí máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rédíò tàbí kí wọ́n máa lọ sí rédíò Nàìjíríà àwọn òṣìṣẹ́ kọ̀ọ̀kan sì faramọ́ pé kí wọ́n ó máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀ Iléiṣẹ́ yìí wà ní Àpáta Yàkùbá ní ọ̀nà tí ó lọ sí Jẹ́bà ní ìlú Ìlọrin Iléiṣẹ́ yìí ni ẹ̀rọ kílówátì mẹ́wàá méjì àti ẹ̀rọ kílówátì mẹ́wàá ní Àpáta Yàkùbá Àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyí ni wọ́n jogún tí ó sì ti gbó Ọ̀kan nínú méjèèjì ni ó ń ṣiṣẹ́ dáadáa ní ọdún Ní ìjọba ilẹ̀ Nàìjíríà fi kún agbára ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ rédíò nípasẹ̀ ìlànà tí wọ́n fi fi iléiṣẹ́ rédíò Nàìjíríà fún ìjọba ìpínlẹ̀ Iléiṣẹ́ yìí ní ẹ̀rọ ńlá méjì ní BùdóẸ̀fọ́ Ìjọba ìpínlẹ̀ náà ri ẹ̀rọ ìgbàlódé kílówátì mẹ́wàá mẹ́rin sí ibi tí ó jìnnà sí ìlú kí wọ́n le máa gbọ́ wọn dáadáa Wọ́n ri méjì sí Ẹ̀gbẹ̀ ọ̀kan sí Otite ní itòsí Okene méjì wà ní ìpínlẹ̀ Kogi báyìí ẹlẹ́kẹ̀rin ni wọ́n rì sí koro ní tuntun ní ìpínlẹ̀ Gbogbo àwọn iléiṣẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n parí wọn tí wọ́n sì kò wọn jáde Pẹ̀lú gbogbo ìdàgbàsókè wọ̀nyí ní ọdún iléiṣẹ́ náà tó wà ní BùdóẸ̀fọ́ dojú kọ ìṣòro ńlá èyí tó jẹ́ pé àrá sán lu ẹ̀rọ gàgàra tí wọ́n rì èyí tí ó sì bàjẹ́ Ìṣòro yìí wá jẹ́ ìpèníjà fún iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ nítorí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iléiṣẹ́ wọn ní èyí tí wọ́n máa ń lò láti fi ṣe àwọn iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan Ní àárín ọdún àtúnṣe iléiṣẹ́ náà wáyé wọ́n sì ri ẹ̀rọ tuntun kan àti alátagbà àádọ́ta kílówátì fún ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba gbìyànjú láti pèsè ẹ̀rọ wọ̀nyí ṣùgbọ́n kò tó fún ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tó rinlẹ̀ Ìjọba Gómìnà Bùkọ́lá Sàràkí ní kété tí ó di gómìnà ní oṣù karùnún ọdún ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àtúnṣe iléiṣẹ́ náà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìgbàlódé ọ̀ọ́dúnrún mílọ́ọ̀nù náírà N ni ó lò láti fi ra ẹ̀rọ ìgbàlódé àti láti fi tún iyàrá ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà ṣe Iṣẹ́ àtúnṣe yìí mú kí rédíò ìpínlẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iléiṣẹ́ tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iléiṣẹ́ tí ó tẹ̀lé òfin pé kí àwọn iléiṣẹ́ rédíò ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìgbàlódé Lábẹ́ òfin tí wọ́n pè ní ni wọ́n fi dá iléiṣẹ́ yìí sílẹ̀ Ní ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iléiṣẹ́ yìí àwọn alákòóso wọn máa ń jẹ́ àwọn tí wọ́n kúnjú òṣùwọ̀n lára àwọn òṣìṣẹ́ wọn ṣùgbọ́n ní òde òní tí ìṣèlú wà nílẹ̀ wa àwọn ẹgbẹ́ ìṣèlú tí ó bá wà lórí àléfà ni ó máa ń yan àwọn tí yóò jẹ́ alákòóso wọn Kò sí òfin tí ó de yíyan àwọn alákòóso wọn ÀWÙJỌ TÍ ILÉIṢẸ́ RÉDÍÒ ÌPÍNLẸ̀ WÀ Ṣé mo kò ó a máa lápèjúwe iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ wà ní ìpínlẹ̀ Ìpínlẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tí ó wà ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà Gómìnà ìpínlẹ̀ ni Bùkọ́lá Sàràkí A ní ẹ̀yà Yorùbá Núpé Baruba àti Fulani ní ìpínlẹ̀ náà Ní ọjọ́ kẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ọdún nígbà ìjọba ológun Yakubu Gowon ni wọ́n dá ìpínlẹ̀ sílẹ̀ Ìpínlẹ̀ àti Kabba jọ wà tẹ́lẹ̀ ni ṣùgbọ́n ní ọdún ní ìpínlẹ̀ náà tó kéré nígbà tí wọ́n dá àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn sílẹ̀ ní orílẹ̀èdè wa Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì ọdún àti Dekina ni wọ́n yọ kúrò lára ìpínlẹ̀ tí wọ́n sì so pọ̀ mọ́ ìpínlẹ̀ Benue Ní ọjọ́ kẹ́tàdínlógún oṣù kéje ọdún ìjọba ìbílẹ̀ márùnún ni wọ́n yọ kúrò lára ìpínlẹ̀ lára wọn ni Oyi Yagba Okene Okehi àti Kogi láti kún ìpínlẹ̀ Kogi ẹlẹ́kẹ̀ẹfà ni tí wọ́n yọ láti fi kún ìpínlẹ̀ Ní báyìí ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìndínlógún ni ó wà ní ìpínlẹ̀ àwọn náà ni; Asà Èkìtì Ìfẹ́lódùn Ìlà Oòrùn Ìlọrin Gúúṣù Ìlọrin Ìwọ̀ Oòrùn Ìlọrin Ìrẹ́pọ̀dùn Ìsin Kiama Moro Ọ̀fà ÒkèẸ̀rọ́ Ọ̀yun Pategi Àwọn ibùdó ìgbafẹ́ tí ó wà ní ìpínlẹ̀ ni ilé àkójọpọ̀ ohun àtàtà àti ohun ìṣẹ̀ǹbáyé ní ìlú Èsìẹ́ Esie ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìrẹ́pọ̀dùn Òkè tí omi ti ń dà ní Ọwá Onírè Owu àpáta ààbò Imoleboja Ogunjokoro Imoleboja Ogunjokoro ọgbà ẹranko tí omi adágún àti Òkè Agbọnna Agbọnna Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ó jẹ́ olórí ètò ọrọ̀ajé wọn ní ìpínlẹ̀ wọ́n sì máa ń gbin kòkó obì kọfí kọ́tìnì àti ọ̀pẹ Wọ́n ní àwọn iléiṣẹ́ tí ó máa ń mówó wálé fún ìjọba ìpínlẹ̀ náà Ní ìpínlẹ̀ yìí wọ́n ní iléẹ̀kọ́ gíga onírúurú bí i ilé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ilé ẹ̀kọ́ gíga Gbogbonìṣe méjì àti ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni onípò kìíní méjì Pẹ̀lú àbájáde iye ènìyàn ní ọdún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ yìí jẹ́ ní ọdún àwọn ènìyàn na jẹ́ ipò ọgbọ̀n sì ni ìpínlẹ̀ wà nínú àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tí ó wà ní orílẹ̀èdè wa Nínú ìwádìí tí a ṣe lórí ẹ̀rọ ayélujára èdè méje ni wọ́n ní gẹ́gẹ́ bí èdè àkọ́kọ́ èdè tí ó sì pọ̀ jù ni èdè Yorùbá Àwọn náà sì ni ẹ̀yà tí ó pọ̀ jù ní ìpínlẹ̀ Èyí túmọ̀ sí pé àwọn ènìyàn Yorùbá ni ó pọ̀ jù ní ìpínlẹ̀ nínú ìdá mẹ́wàá ìdá mẹ́jọ ni àwọn ẹ̀yà Yorùbá tí ó sì ń sọ èdè Yorùbá Púpọ̀ àwọn ètò tí wọ́n ń ṣe ní rédíò ètò Yorùbá ni ó pọ̀ ju àwọn ètò yòókù lọ gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí a ṣe ní iléiṣẹ́ rédíò Èyí túmọ̀ sí pé èdè Yorùbá ni èdè tí ó tayọ ju àwọn èdè yòókù lọ nínú àwọn èdè àti ètò tí wọ́n ṣe lórí rédíò yìí OJÚṢE ILÉIṢẸ́ RÉDÍÒ ÌPÍNLẸ̀ Mélòó la ó kà nínú eyín adípèlé ni ọ̀rọ̀ ojúṣe iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ ṣùgbọ́n kí á tó mẹ́nuba àwọn ojúṣe wọ̀nyí a ó kọ́kọ́ sọ ojúṣe iléiṣẹ́ rédíò lápapọ̀ Ọ̀kan lára ojúṣe iléiṣẹ́ rédíò ni pé wọ́n máa ń jábọ̀ ìròyìn wọ́n sì máa ń fún ìròyìn ní ìtumọ̀ Òmíràn ni pé wọ́n máa ń dá àwọn ará ìlú lárayá wọ́n sì máa ń kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ètò ọlọ́kanòjọ̀kan tí wọ́n máa ń ṣe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ ní àwọn ojúṣe mìíràn tí ó yàtọ̀ sí ti iléiṣẹ́ rédíò lápapọ̀ tí wọ́n là kalẹ̀ fún ara wọn Àwọn ojúṣe wọ̀nyí ni ó wà ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ tí ìjọba gbé kalẹ̀ fún ìdásílẹ̀ iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ Lára àwọn ojúṣe iléiṣẹ́ náà nìwọ̀nyí Láti ṣe ìdìde àti ìdàgbàsókè iléiṣẹ́ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá fún iléiṣẹ́ wọn Èyí ń pé àṣẹ yìí gbà wọ́n láàyè láti dá iléiṣẹ́ mìíràn sílẹ̀ tí wọn yóò ti máa gbé àwọn ètò wọn jáde tàbí tí yóò máa ṣe ìrànwọ́ fún ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ iléiṣẹ́ wọn Láti ṣe ìtọ́jú iléiṣẹ́ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá iléiṣẹ́ wọn nípa pípèsè àwọn ohun èlò tí iléiṣẹ́ yìí nílò bí i ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti yàrá ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìgbàlódé ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti fọ́nrán téèpù Wọ́n ní àǹfààní láti gba ìròyìn agbègbèkágbègbè ní àgbáyé fún ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ èyí tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ tí orílẹ̀èdè Nàìjíríà gbé kalẹ̀ ní ọdún Láti ṣe ìkéde ohun tí a kọ sílẹ̀ tàbí kọ sínú ìwé tí ó le ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwùjọ Láti ṣe ohunkóhun tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ iléiṣẹ́ yìí àti ṣe àtúnṣe àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò fún ìdàgbàsókè iléiṣẹ́ yìí Wọ́n ní àǹfààní láti kópa tàbí darapọ̀ mọ́ ìdásílẹ̀ àwọn iléiṣẹ́ aládàáni nípa ìpín nínú ìdókòwò iléiṣẹ́ aládàáni bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ìdásílẹ̀ iléiṣẹ́ ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà Láti yan ẹnikẹ́ni láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdarí irú iléiṣẹ́ aládàáni bẹ́ẹ̀ Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ Tí a bá fi ojú tíọ́rì ìmọ̀ ìbáraẹnigbépọ̀ àwùjọ wo àwọn ojúṣe wọ̀nyí a ó rí i pé àwọn ojúṣe wọ̀nyí wúlò púpọ̀ fún àwùjọ tí wọ́n sì jẹ́ èyí tí ó ṣe àwọn ará ìlú ní àǹfààní kan tàbí òmíràn Tíọ́rì yìí jẹ́ kí a rí i pé àwọn ètò tí iléiṣẹ́ yìí ń gbé sáfẹ́fẹ́ wà ní ìbámu pẹ̀lú ètò tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń lọ lọ́wọ́ ní àwùjọ Ó jẹ́ kí á mọ̀ pé àwọn ènìyàn àwùjọ gan an ni iléiṣẹ́ yìí wà fún ìbáṣepọ̀ tí ó sì dán mọ́rán gbọdọ̀ wà láàárin iléiṣẹ́ yìí àti àwùjọ Àwọn òṣìṣẹ́ iléiṣẹ́ yìí wà láti inú ẹ̀ka ìròyìn ìkéde ìpolówó ọjà ìpolongo àwọn ohun wọ̀nyí wà láti inú àwùjọ ó sì tún wà fún àwọn àwùjọ Ajólórí tíọ́rì yìí ni ènìyàn àwùjọ àti ìbáṣepọ̀ wọn àti ipa tí irú ìbáṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ ní lórí àwùjọ Ohun tí ó jẹ tíọ́rì yìí lógún jù ni ìgbé ayé ẹ̀dá nínú àwùjọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ àṣà rẹ̀ ìwà rẹ̀ àti èdè rẹ̀ èyí tí ó jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ẹ̀dá dúró lé Gbogbo nǹkan tí tíọ́rì yìí fúnka mọ́ ni ó wà nínú ojúṣe iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ tí ó sì mú kí ìbáṣepọ̀ wà láàárín iléiṣẹ́ yìí àti àwùjọ ÈTÒ YORÙBÁ NÍLÉ IṢẸ́ RÉDÍÒ Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni ó gbé iléiṣẹ́ rédíò wá sílẹ̀ Nàìjíríà Àwọn ètò tí wọ́n sì ń gbé sórí afẹ́fẹ́ jẹ́ ètò lédè Gẹ̀ẹ́sì Àwọn ètò wọ̀nyí jẹ́ ètò tí wọ́n fi ń ránṣẹ́ láti ìlú ọba Àwọn oníṣẹ́ iléiṣẹ́ a sì máa gba ètò náà sílẹ̀ wọn yóò sì túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Yorùbá Ṣùgbọ́n ìwádìí tí a ṣe lórí rédíò ìpínlẹ̀ fi hàn wá pé ní kété tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹ́rin ọdún ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ètò ní èdè Yorùbá Kì í ṣe pé wọ́n ń gba ètò sílẹ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n sì ń túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Yorùbá bí kò ṣe pé èdè Yorùbá gan an ni wọ́n ń ṣe àwọn ètò tí wọ́n ń ṣe ní èdè Yorùbá Tí a bá wo ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ètò Yorùbá ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Yorùbá tí a mẹ́nubà pé ó pọ̀ jù ní ìpínlẹ̀ A rí i pé àkókò tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ètò Yorùbá bójúmu nítorí tí a bá fojú tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì wò ó a rí i pé ohun tí ó jẹ tíọ́rì yìí lógún ni ìgbé ayé ẹ̀dá nínú àwùjọ ìgbàgbọ́ àṣà ìwà àti èdè rẹ̀ èyí tí ó jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ẹ̀dá dúró lé; nítorí náà èdè jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ó ṣe pàtàkì sí ènìyàn èdè sì ni wọ́n fi ń gbé ètò sórí afẹ́fẹ́ iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ ètò Yorùbá ní àkókò tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ Nítorí náà a lè sọ pé àjọṣepọ̀ iléiṣẹ́ rédíò àti àwùjọ dán mọ́rán nítorí wọ́n mọ èdè tí àwọn àwùjọ ń sọ pàápàá jùlọ èdè ẹ̀yà tí ó pọ̀ jù nínú àwùjọ náà èdè yìí sì ni wọ́n ń lò láti gbé ètò sórí afẹ́fẹ́ fún ìgbádùn aráàlú ÀGBÉKALẸ̀ ÀWỌN ÈTÒ ORÍ RÉDÍÒ Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí a ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ètò orí rédíò fún ọdún mẹ́ta sẹ́yìn bẹ́ẹ̀ ni a ṣe àgbéyẹ̀wò iye wákàtí tàbí ìṣẹ́jú tí wọ́n ń lò fún àwọn ètò wọ̀nyí fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fún àwọn ọdún wọ̀nyí; a sì wò ó ní ìbámu pẹ̀lú àwùjọ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ A ṣe àkànpọ̀ àwọn ètò wọ̀nyí sábẹ́ ìjẹyọ márùnún báyìí; Àṣà ọmọlaṣọ ìmọ́tótó àgbẹ̀lérè akínkanjú ọdẹ àlọ́ o ọmọ Oòduà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ìṣíde ìṣíde Ìròyìn ìròyìn láfẹ̀mọ́jú ìròyìn ní ṣókí ìròyìn lápapọ̀ ìròyìn lábẹ́lé Amúlùúdùn fìgbádùn ṣayọ̀ olékenkà ilé aláyọ̀ lágbo ìgbàlayé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ẹ̀sìn wáàsí ìdájí àṣàrò Kìrìsítíánì májẹ̀mú ọ̀nà ìgbàlà ẹwà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ÈTÒ FÚN ỌDÚN ỌJỌ́ ÈTÒ ÀKÓKÒ Àìkú Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan Ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ajé Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún Ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ìṣẹ́gun Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan àti àádọ́ta ìṣẹ́jú Ìṣẹ́jú márùnún Ọjọ́rú Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú mẹ́fà Wákàtí méjì Wákàtí kan àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Ọjọ́bọ Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Wákàtí kan àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Wákàtí méjì àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ẹtì Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú mẹ́fà Wákàtí méjì Wákàtí kan àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Àbámẹ́ta Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan Wákàtí kan Wákàtí mẹ́ta àti ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún Ìṣẹ́jú mẹ́wàá ÈTÒ FÚN ỌDÚN ỌJỌ́ ÈTÒ ÀKÓKÒ Àìkú Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí méjì àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú méjì Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ajé Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Àádọ́ta ìṣẹ́jú Wákàtí kan Wákàtí méjì àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ìṣẹ́gun Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí méjì àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Wákàtí kan Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta Ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ọjọ́rú Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún Wákàtí kan Wákàtí mẹ́ta àti ìṣẹ́jú márùnún Ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ọjọ́bọ̀ Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí mẹ́ta Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta Ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ẹtì Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta Wákàtí kan Wákàtí kan àti ogún ìṣẹ́jú Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùndínlógójì Àbámẹ́ta Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún Wákàtí kan Wákàtí kan àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Ìṣẹ́jú mẹ́wàá ÈTÒ FÚN ỌDÚN ỌJỌ́ ÈTÒ ÀKÓKÒ Àìkú Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí méjì àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú méjì Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún Wákàtí méjì àti ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ajé Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta Wákàtí kan Wákàtí kan àbọ̀ Ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ìṣẹ́gun Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Wákàtí kan Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta Ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ọjọ́rú Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún Wákàtí kan Wákàtí mẹ́ta àti ìṣẹ́jú márùnún Ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ọjọ́bọ̀ Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí mẹ́ta Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta Ìṣẹ́jú mẹ́wàá Ẹtì Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta Wákàtí kan Wákàtí kan ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùndínlógójì Àbámẹ́ta Ìṣíde Àṣà Ìròyìn Amúlùúdùn Ẹ̀sìn Ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún Wákàtí kan Wákàtí mẹ́ta àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú Ìṣẹ́jú mẹ́wàá ÀGBÉKALẸ̀ ÈTÒ YORÙBÁ LỌSẸ̀ FIHÀN PÉ; ỌJỌ́ ÈTÒ Àìkú Wákàtí mẹ́rin àti ogójì ìṣẹ́jú Wákàtí méjì àti ìṣẹ́jú méjì Wákàtí méjì àti ìṣẹ́jú méjì Ajé Wákàtí mẹ́ta àti ìṣẹ́jú márùnúndínlógójì Wákàtí mẹ́ta àti ogójì ìṣẹ́jú Wákàtí mẹ́ta àti ogójì ìṣẹ́jú Ìṣẹ́gun Wákàtí márùnún àti ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí mẹ́rin àti ogójì ìṣẹ́jú Wákàtí mẹ́rin àti ogójì ìṣẹ́jú Ọjọ́rú Wákàtí mẹ́ta àti àádọ́ta ìṣẹ́jú Wákàtí márùnún àti ìṣẹ́jú márùndínlógójì Wákàtí márùnún àti ìṣẹ́jú márùndínlógójì Ọjọ́bọ̀ Wákàtí márùnún àti ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta Wákàtí méje àti ìṣẹ́jú márùnún Wákàtí méje àti ìṣẹ́jú márùnún Ẹtì Wákàtí márùnún àti ìṣẹ́jú mọ́kànlá Wákàtí mẹ́rin àti ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta Wákàtí mẹ́rin àti ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta Àbámẹ́ta Wákàtí méjì àti ìṣẹ́jú méjìléláàdọ́ta Wákàtí mẹ́rin Wákàtí mẹ́rin Pẹ̀lú àtẹ yìí a rí i pé wọ́n fààyè gba ètò Yorùbá ní ọdún àti ju ti lọ èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí bí ilé ayé ṣe ń yí ni iléiṣẹ́ yìí náà ń yí wọ́n kò dúró sojú kan àwọn ohun ọ̀tun àti ètò ọ̀tun ń wọnú àwọn ètò wọn Àwọn ètò wọ̀nyí sì máa ń dálé ohun tó ń lọ láwùjọ tí ó sì ń fi ìbáṣepọ̀ àwùjọ hàn gẹ́gẹ́ bí tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì ṣe sọ Àtẹ yìí sì jẹ́ kí a rí àkókò tí à ń lò fún àwọn ètò wọ̀nyí ó sì tún jẹ́ kí a rí iye àkókò tí à ń lò fún ètò Yorùbá lórí rédíò ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan Ètò ìṣíde jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń lò láti fi ìṣíde àwọn ètò wọn ní àràárọ̀ ìṣẹ́jú márùnún sì ni wọ́n máa ń lò Ètò ìṣíde yìí ni wọ́n máa ń lò gẹ́gẹ́ bí ìwúre tàbí ìjúbà Wọ́n gbàgbọ́ pé nínú ohun gbogbo ó yẹ kí á fi Ọlọ́run sáájú wọ́n gbàgbọ́ pé igbá tí a bá fi lé Ọlọ́run lọ́wọ́ kì í ya àwo tí a sì fi lé Ọlọ́run lọ́wọ́ kì í fọ́ Wọ́n a máa ṣe ìṣíde kí àwọn ètò náà má ba à hun wọ́n wọ́n a sì tún máa lò ó láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó dáwọn sí di ọjọ́ náà Nínú àwọn ètò yòókù a rí i pé ètò tó jẹmọ́ àṣà ni wọ́n fààyè gbà jùlọ yàtọ̀ sí ọjọ́ àìkú tí iye àkókò tí wọ́n máa ń lò fún ẹ̀sìn ju ti àṣà lọ èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ọjọ́ àìkú yìí ni ọjọ́ ìsìn àwọn Ọmọlẹ́yìn Kírísítì Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ẹtì náà jẹ́ ọjọ́ tí àwọn Mùsùlùmí máa ń lọ jọ́sìn a rí i pé àkókò tí wọ́n ń lò fún ẹ̀sìn lọ́jọ́ àìkú tayọ ti ọjọ́ ẹtì Nítorí náà àwọn Ọmọlẹ́yìn Kírísítì máa ń lo ọjọ́ yìí láti kéde ìhìnrere Kírísítì fún àwọn ènìyàn okùnfà èyí wà ní orí iṣẹ́ yìí Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ sáájú a rí i pé ètò tí ó jẹ mọ́ àṣà ni iléiṣẹ́ yìí fààyè gbà jù A lè sọ pé àwọn iléiṣẹ́ yìí rí àṣà bí òpómúléró àwùjọ nínú àṣà ni a ti máa ń rí òfin àti èèwọ̀ Wọ́n rí àṣà gẹ́gẹ́ bí amáyégún àti amáyéró àṣà jẹ́ ohun tí a máa ń lò láti kọ́ ẹ̀kọ́ ìwà ọmọlúàbí Lára irú àwọn ètò báyìí ni a ti rí ìmọ́tótó; Yorùbá ní ìmọ́tótó borí ààrùn gbogbo mọ́lẹ̀ wọn a máa gbé àwọn Oníṣègùn ìlera ara wá tàbí àwọn woléwolé láti wá dá àwọn aráàlú lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlera ara àti gbígbé ìgbésí ayé àlàáfíà nígbà mìíràn wọn a sì máa kéwì fún àwọn aráàlú lórí ìmọ́tótó Àgbẹ̀lérè; ètò yìí máa ń sọ pàtàkì iṣẹ́ àgbẹ̀ fún wa èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan lára iṣẹ́ ìṣẹ̀ǹbáyé Yorùbá wọ́n á ní bébi bá kúrò nínú ìṣẹ́ àbùṣebùṣe Ọbẹ̀làwọ̀; ètò yìí ni wọ́n máa ń lò láti kọ́ àwọn obìnrin wa ní ọ̀nà tí à máa ń gbà láti tọ́jú ọkọ àti ọmọ ẹni wọn a ní ọlọ́bẹ̀ ló lọkọ Àlọ́ o; ètò yìí ni wọ́n máa ń lò láti kọ́ àwọn ọmọdé ní ẹ̀kọ́ ìwà ọmọlúàbí Yorùbá sì gbàgbọ́ pé nígbà tí ọwọ́ bá dilẹ̀ ni a máa ń pàlọ́ fún àwọn ọmọdé gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìdárayá àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ A sì rí i pé ìgbà tí wọ́n máa ń ṣètò àlọ́ o ni àsálẹ́ tí ọ̀wọ́ bá dilẹ̀ tán lẹ́yìn iṣẹ́ òòjọ́ ìyẹn ní aago méje alẹ́ sí méje kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún ORÍ KẸ́RIN ÈTÒ YORÙBÁ LÓRÍ RÉDÍÒ ÌPÍNLẸ̀ ÌFÁÀRÀ Ní orí kẹ́rin iṣẹ́ yìí ni a ó túṣu dé ìsàlẹ̀ kókó lórí àwọn ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí àgbékalẹ̀ àwọn ètò wọ̀nyí tí a ti ṣe ní orí kẹ́ta iṣẹ́ yìí A rí i pé a ní ètò tó jẹ́mọ́ ìṣíde àṣà ìròyìn ámulùúdùn àti ẹ̀sìn Nínú iṣẹ́ yìí ni a ti ṣe alàkalẹ̀ àwọn ètò wọ̀nyí a ó wo ipa àti ìwúlò àwọn ètò Yorùbá ìṣòro tí ètò Yorùbá ń dajú kò nílé iṣẹ́ yìí a óò sí wo ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìṣòro wọ̀nyìí Á ó ṣì ṣe lámèyítọ́ lórí àwọn ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ ÀLÀKALẸ̀ ÀWỌN ÈTÒ YORÙBÁ LÓRÍ RÉDÍÒ ÌPÍNLẸ̀ Nínú ìfáàrà wa a ti mẹ́nu bàá pé a óò ṣe àlàkalẹ̀ àwọn ètò Yorùbá tó jẹmọ́ ìṣíde àṣà ìròyìn ámulùúdùn àti ẹ̀sìn Ohun pàtàkì tí a óò ṣe nínú rẹ̀ ni láti ṣe àlàkalẹ̀ àwọn ètò tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn ìsọ̀rí ètò tí a mẹ́nu bà ÌṢÍDE Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé ṣáájú ohun gbogbo Olódùmarè ni ó yẹ kí ó ṣáájú Ìgbàgbọ́ wọn ni pé Olódùmarè ni àkọ́dá ayé àti aṣẹ̀dá ọ̀run Nítorí náà nínú ètò ìṣíde wọn Olódùmarè ni wọ́n máa ń fi í ké pè Ewì kíké sì ni wọ́n máa ń lò fún ètò ìṣíde yìí Lẹ́yìn tí wọ́n bá kí Olódùmarè tán wọn yóò wá sọ kókó ohun tí wọ́n fẹ́ kí àwọn ènìyàn dìmú nínú ewì wọn Ohun tí à ń sọ ni pé ó máa ń ní kókó tí wọ́n fẹ́ fi ewì yìí ṣe yálà láti kọ́ni lẹ́kọ́ ìwà ọmọlúàbí yàtọ̀ sí pé wọ́n fi kí Olódùmarè Ìlànà ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ni ó máa ń tẹ̀lé ṣùgbọ́n wọ́n máa ń fi tí ẹ̀sìn Mùsùlùmí àti Kìrìsìtẹ́nì bọ̀ ọ́ láàárín ÀṢÀ Yorùbá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà tí ó lajú jù lóde ayé yìí Láti ìgbà tí àlàyé ti dáyé ni wọ́n ti ní ètò àti ìlànà tó kún nípa ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe ní ìgbésí ayé wọn Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àkọsílẹ̀ àwọn ètò àti ìlànà wọ̀nyí gbogbo wọn ni àwọn Yorùbá mọ̀ dáadáa tí wọ́n sì ń lò lojoojúmọ títí ó fi di barakú tàbí àṣà fún wọn Nígbà mìíràn ọ̀pọ́ ènìyàn máa ń wo àwọn ètò àti ìlànà wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn kan nítorí tọkàntọkàn ni àwọn Yorùbá fi ń tẹ̀lé wọn Ara wọn ni àṣà ìdeyún àti ìgbẹ̀bí ìkómọ àti ìsọmọlórúkọ ìranraẹnilọ́wọ́ iìsìnkú àti ogún jíjẹ àti oge ṣiṣẹ́ Ètò tún wà fún ijọbá ṣíṣe iṣẹ́ ṣíṣ ere ṣíṣe iṣẹ́ kíkọ́ ogun jíjà ìjà lìlà ẹbí ṣíṣe àti àdúrà ṣíṣe Ilé iṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ mọ̀ àwọn ètò àti àṣà Yorùbá yìí wọ́n sì ń tẹ̀lẹ̀ wọn Wọ́n máa ń lọ ètò wọ̀nyí láti kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìwà ọmọlúàbí àti láti kọ́ wọn lọ́gbọ́n Lára àwọn ètò wọn tí wọ́n ń lò fún ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ni Ọbẹ̀làwọ̀ Ó jẹ́ ètò kan tí ó jẹ mọ́ àṣà Yorùbá Ètò yìí ni wọ́n máa ń lò láti kó àwọn obìnrin ní ẹ̀kọ́ ìtójú ilé Bí wọ́n ṣe ń tọ́jú oko àti ọmọ tí wọn fi ń dùn ún rí láwùjọ Wọ́n máa ń fi ètò yìí kọ́ àwọn obìnrin ní onírúurú óúnjẹ ti wọ́n le ṣe fún ilé wọn; ọlọ́bẹ̀ ló lọkọ; ọbẹ̀ kò dùn ọkọ kò jẹ; gbèsè dé ọkọ yẹrí nítorí náà ọ̀nà láti máa jẹ́ kí ọkọ yẹrí ni wọ́n máa ń kọ àwọn obìnrin àti ọ̀nà tí wọn yóò gbà ṣe ìmọ̀tótó ilé wọn tí yóò fi dùn u rí Ọmọlaṣọ náà jẹ́ ètò kan tí wọ́n ń lò láti kó àwọn òbí ní ọ̀nà tí à ń gbà tójú ọmọ wọ́n máa ń fi ètò yìí kọ́ àwọn òbí pé ọmọ ni ọjọ́ ọlá ẹni ọmọ tí a kò bá sì kọ́ yóò gbé ilé tí a kọ́ tà Wọ́n máa ń fi ètò yìí sọ fún àwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn pé agbójúlógún fira rẹ̀ fóṣì tà Kókó ètò yìí sí àwùjọ ni pé ìtọ̀jú ọmọ ṣe pàtàkì nítorí ọmọ ẹni ni ẹ̀yìnwá ọlá Agbára mọ̀ọ́nkọ mọ̀ọ́nkà jẹ́ ètò tí wọ́n ń lò láti kọ́ àwọn ọmọdé ni èdè Yorùbá Bí a ṣé ń kọ èdè Yorùbá àti ka èdè yìí ni ó jẹ́ wọ́n lógún Pàtàkì ètò yìí ni láti tan èdè Yorùbá ka àti àṣà wa Àlọ́ o jẹ́ ètò tí ó wà fún ìdárayá ìdánìlẹ́kọ̀ọ́ ìkọ́ni ní ìwà ọmọlúàbí wọ́n sí tún má ń lòó láti mọ bí ọpọlọ ọmọ kọ̀ọ̀kan ṣe jáfárá sí tàbí bí ó ṣe kú sí Àlọ́ àpamọ̀ tàbí àpagbè ni wọ́n fi máa ń ṣe ìdáraya fún àwọn ọmọdé; wọ́n sì máa ń lọ àlọ́ onítan láti kọ́ àwọn ọmọdé ní ẹ̀kọ́ ìwà ọmọlúàbí Bákan náà wọ́n máa ń lọ àlọ́ láti jẹ́ kí àwọn ọmọ ní ẹ̀mí ìranraẹnilọ́wọ́ Pàtàkì ètò àlọ́ sí àwùjọ ní ìdánilẹ́kọ́ọ̀ ìwà ọmọlúàbí Àwọn ètò mìíràn ni Àgbẹ̀lérè Àgbẹ̀lọba Akínkanjú ọde Àwọn ètò wọ̀nyí ni wọ́n máa ń lò láti kọ́ àwùjọ nípa iṣẹ́ ìṣènbáye wa Wọ́n máa ń lọ àwọn ètò wọ̀nyí láti jẹ́ kí á mọ pàtàkì tí ó wà nínú iṣẹ́ agbẹ Láti ìbéèrè pẹ̀pẹ̀ ni Yorùbá ti káràmáásìkí iṣẹ́ ṣíṣe ìdí nìyí tí a máa ń fi i gbọ́ iṣẹ́ ni òògùn iṣẹ́ iṣẹ́ kì í pani àìse rẹ̀ gan ni ìjàngbọ̀n wọn a ní bí ebi ń pa ọ̀lẹ ẹ jẹ́ ó kú kíkú tàìkú ọ̀lẹ ó wúlò Gbogbo ìpèdè wọ̀nyí ń tọ́ka sí bí ìran Yorùbá ṣe káràmáásìkí iṣẹ́ ṣíṣe ní àwùjọ wọn Nílẹ̀ Yorùbá a ni iṣẹ́ ìdílé tàbí iṣẹ́ àtìrandéran lára wọn ni iṣẹ́ alágbẹ̀dẹ iṣẹ́ ìlú lílù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ṣùgbọ́n iṣẹ́ àgbẹ̀ kì í ṣe ìṣe ìdílé iṣẹ́ tí gbogbo ènìyàn le ṣe ni Ìdí nìyí tí wọ́n fi gbé ètò yìí kalẹ fún mùtúmùwà láti rí ẹ̀kọ́ kan kọ́ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ àgbẹ̀ méjì tí a ní ní wọ́n sí máa ń pààlà sí fún wa iṣẹ́ àgbẹ̀ aláàdá ńlá àti alárojẹ Pàtàkì àwọn ètò wọ̀nyìí ni láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn rí èèrè tí ó wà nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ kí àwọn náà sì lè máa ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ níwọ̀n ba tí agbára wọn bá ká Pàtàkì ètò yìí mìíràn ni pé wọ́n fẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ iyi àwọn àgbẹ̀ wọ́n sí tún máa ń fi ń gbórìyìn fún àwọn àgbẹ̀ Gbogbo àwọn ètò tí ó jẹmọ́ àṣà ń wọ́n máa ń ṣe ní ìrọ̀lẹ́ sí alẹ́ Ìdí ni pé àwọn ènìyàn àwùjọ yóò ti ti ibi iṣẹ́ òòjọ́ wọn dé wọn yóò sì ráàyè láti gbọ́ ètò wọ̀nyìí Ti a bá wo àkókò lẹ́yìn tí àwọn Yorùbá máa ń dára wọn láraya a rí i pé lẹ́yìn iṣẹ́ òòjọ̀ ní ìgbà tí ọwọ́ bá dilẹ̀ ni Àkókò tí àwọn ètò wọ̀nyí máa ń wáyé náà sì bá tí àwùjọ Yorùbá mu ÌRÒYÌN Yorùbá bọ̀ wọ́n ni kókó ni à ń rán etí adití Ajọlórí ìròyìn ni láti jábọ́ ìsàlẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú fún àwùjọ Nínú ètò ìròyìn ilẹ̀ iṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ wọ́n ní ìròyìn ní ṣókí ìròyìn labẹlè àti ìròyìn lápapọ̀ Ìròyìn ní ṣókí ni ìròyìn tí wọ́n máa ń múwá sétìgbọ́ aráàlú ní wákàtí wákàtí láti máa fi ohun tó ń lọ ní àwùjọ tó àwọn aráàlú léti lóòrèkóòrè Ìròyìn lábẹ́lé ni ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń lọ ní agbègbè tàbí àdúgbò tí ilé iṣẹ́ yìí wà Ó sáábà máa ń jẹ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ ìpínlẹ̀ Ìròyìn lápapọ̀ ni àkójọpọ̀ ìròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àgbáyé Ó máa ń kún fún ìròyìn ìbílẹ̀ ìpínlẹ̀ orílẹ̀ èdè àti àgbáyé Nínú ìjábọ̀ ìròyìn ó ní ìlànà tí àwọn akàròyìn gbọdọ̀ tẹ̀lé Gbogbo àwọn ìlànà wọ̀nyí sí ni àwọn akàròyìn ilé iṣẹ́ yìí máa ń tẹ̀lé Ikíni ni ó máa ń ṣáájú tí ìfáàrà sí ìròyìn tí akàròyìn fẹ́ mú wá àti dídárúkọ akàròyìn máa ń tẹ̀lé Ṣíṣe àfihàn ilé iṣẹ́ tí a ti múròyìn wá ni ó máa ń tẹ̀lé Oníròyìn yóò sọ kókó inú ìròyìn láti jẹ́ kí olùgbọ́ ní òye ohun tí yóò ṣe alábàpàdé nínú ìròyìn Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn ni ó kàn Ìgbésẹ̀ yìí ṣe pàtàkì nítorí oníròyìn gbọdọ̀ ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn tí ó sà jọ Oníròyìn yóò dánu dúró díẹ̀ láti ṣe àfihàn iléiṣẹ́ tó ti ń ka ìròyìn Lẹ́yìn kíka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn ní ìparí rẹ̀ ni àkàròyìn yóò ti tún kókó inú ìròyìn náà sọ fún àwọn olùgbọ́ Akàròyìn yóò sì ṣe ìkíni ìkádìí ìròyìn rẹ̀ Èyí fihàn pé ìròyìn ní ìlànà tàbí ààtò tí àwọn akàròyìn gbọdọ̀ tẹ̀lé nínú kíka ìròyìn Bákan náà akàròyìn gbọdọ̀ mọ iru àwùjọ tí ó ń bá sọ̀rọ̀ ìlò èdè tó jinle tó múnádóko máa ń jẹyọ nínú àwọn ìròyìn yìí pàápàá sísọ lọ́nà tó gún régé fún òye àwọn olùgbọ́ Pàtàkì àwọn ìròyìn ni láti ta àwọn àwùjọ lólobó sí ohun tó ń lọ ní àwùjọ láti mọ ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé tàbí ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan yóò ṣẹlẹ̀ Lára àwọn ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà sa ìròyìn jọ ni ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò jíjáde lọ sí ìgboro láti gba ìròyìn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ AMÚLÙÚDÙN Gbogbo ọjọ́ kọ́ ni ọdún ní ara ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bẹ́ẹ̀ ni kì í sí ń ṣe gbogbo ọjọ́ ni ọjọ́ orò èyí ni ó mú kí àwọn Yorùbá ní àkókò fún iṣẹ́ àti fún eré Bí àwọn babańlá wa ti fẹ́ràn iṣẹ́ tó ó ní àwọn àkókò tí wọ́n máa ń fi sílẹ̀ fún eré ṣíṣe nínú ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní iléeṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ ó ní àkókò tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn ètò amúlùúdùn Lára àwọn ètò yìí ni a ti rí Jogbo Lágbo Tíátà Yorùbá Ẹkún o oyin mọ mọ Àyọkà Ayọ̀ ìdílé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ètò Jogbo jẹ́ ètò tí wọ́n máa ń lò láti dá àwọn aráàlú lára yá Atọ́kùn ètò yìí máa ń lo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ ní ìlànà ẹ̀fẹ̀ láti múnú àwọn aráàlú dùn àti láti kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ Kókó ètò yìí ni ìdánilárayá àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ Lágbo ni ètò tí ó wà fún ìgbàdún àwọn aráàlú Orin ni wọ́n sábàá máa ń fi ètò yìí kọ sí etíìgbọ́ àwọn aráàlú Wọ́n máa ń lò ó láti tu àwọn aráàlú nínú Pàtàkì ètò yìí gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ Lágbo ni pé wọ́n ń lò ó láti polówó ọtí Ìlò èdè ètò yìí máa ń jẹmọ́ tí àwọn ọmọ ọlọ́kọ̀ tàbí ọmọ ìta ṣùgbọ́n ẹ̀fẹ̀ rẹ̀ máa ń fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sọ Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀fẹ̀ ni atọ́kùn rẹ̀ máa ń jẹmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ tí atọ́kùn yóò sì fi dápará Iléiṣẹ́ ọtí ni ó ṣe onígbọ̀wọ́ ètò yìí ìdí sì nìyí tí ó fi jẹ́ pé ọtí yìí ni wọ́n máa ń polówó Ètò mìíràn ni Tíátà Yorùbá ereoníṣe ni ètò yìí wà fún; ìlànà ìsọ̀rọ̀ǹgbèsì ni wọ́n fi máa ń gbé e jáde Nígbà mìíràn ó le jẹ́ eréoníṣe afẹ̀hónúhàn ìfàwùjọsẹ̀fẹ̀ ẹ̀sìn tàbí ajẹmọ́ ìtàn gidi Ó lè jẹ́ ìwé eréoníṣe Yorùbá kan ni wọ́n yóò lò láti gbé eré náà síta fún aráàlú láti gbádùn Àyọka ni ètò tí wọ́n máa ń ti ń ka ìwé ìtàn àròsọ Yorùbá fún wa Atọ́kùn yóò mu ìwé kan tí yóò sì máa kà á si etí ìgbọ́ àwọn aráàlú ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ Atọ́kùn a máa na ìbéèrè sí ìta fún àwọn aráàlú láti dáhùn yálà kí wọ́n sọ ibi tí wọ́n ka ìtàn náà dé Ẹ̀bùn sì wà fún ẹni tó bá gbà á Ètò yìí wà fún ìdárayá àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìgbádùn aráàlú Ayọ̀ ìdílé ni ètò tí wọ́n máa ń lò fún ìgbádùn aráàlú àti láti kọ́ lọ́kọláyà ní ẹ̀kọ́ nípa ìdílé Bí ìdílé ṣe ń láyọ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn yóò la ìṣòro kọjá ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìforítì wọn yóò borí Wọ́n ń lo ètò yìí láti fi to ìdílé tí ó bá ti dàrú tàbí tí ó ti fẹ́ dàrú sọ́nà Ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìdílé ni wọ́n máa ń nà síta tí wọ́n sì máa ń ṣe é ní ìlànà ìsọ̀rọ̀ńgbèsì àwọn aráàlú yóò sì dá sí ètò láti sọ àṣìṣe ọkọ tàbí aya fún un Ẹ kun o ni wọ́n máa ń lò láti ṣe ìkíni fún àwọn aráàlú Àwọn aráàlú máa ń ra kádìí láti fi ṣe ìkíni sí àwọn ara àti ẹbí wọn wọ́n máa ń sọ fún atọ́kùn láti bá àwọn lu àwo sí etí ìgbọ́ àwọn ará wọn fún ìgbádùn Ẹ̀SÌN Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé Ọlọ́run ló dá ayé tó sì dá àwọn ẹ̀dá inú rẹ̀ àti pé gbogbo àwa ẹ̀dá wá sínú rẹ̀ bí ẹni tó lọ ná ọjà ni tí yóò sì padà relé láti lọ jábọ̀ Yorùbá gbà wí pé àwọn ní láti máa fi orúkọ Ọlọ́run sí ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe láyé nítorí pé bí kò bá sí Ọlọ́run àbá ẹ̀dá kankan kò tiẹ̀ lè ṣẹ́ Ní àwùjọ wa a ní ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ẹ̀sìn Kìrìsítíẹ́nì àti ẹ̀sìn Mùsùlùmí Àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí ni ó gbàgbọ́ pé Ọlọ́run ni ó dá gbogbo ẹ̀dá nílé ayé Wọ́n gbàgbọ́ pé ó ni àwọn òfin kan tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ fún wa láti tẹ̀lé láti máyé gún Àwọn ètò tó jẹmọ́ ẹ̀sìn tí iléiṣẹ́ yìí ń gbé sórí afẹ́fẹ́ ni àti ń tọ́ wa sí ọ̀nà tí a ó ò gbà láti tẹ̀lé òfin wọ̀nyí láti lè máyé gún Àwọn ètò tó jẹmọ́ ẹ̀sìn Kìrìsítíẹ́nì ètò yìí ni wọ́n máa ń lò láti sọ ìrètí tí àwọn Kìrìsítíẹ́nì ní nínú ẹni tí wọ́n gbàgbọ́ Wọ́n máa ń lò ó láti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Kírísítì jinlẹ̀ nínú ìpadàbọ̀ Jésù Wọ́n máa ń fi ètò yìí kéde ìhìnrere Jésù fún àwọn tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Obìnrin Oníwà Rere ni ètò tí wọ́n gbé kalẹ̀ láti kọ́ àwọn obìnrin ní ẹ̀kọ́ ìwà Wọ́n máa ń lò ó láti jẹ́ kí àwọn obìnrin mọ̀ pé ipò àti ojúṣe wọn nínú àwùjọ ìjọ ilé àti ibi iṣẹ́ Wọn máa ń lo ètò yìí láti jẹ́ kí àwọn ọkùnrin rí pàtàkì obìnrin ní àwùjọ Ọ̀nà Ìgbàlà ni ètò tí wọ́n máa ń lò láti wàásù ìhìnrere Jésù fún àwùjọ Wọ́n máa ń lo ètò yìí láti pe àwọn ènìyàn sí inú ẹ̀sìn yìí wọ́n sì máa ń lò ó láti tọ́ àwọn ènìyàn sọ́nà tí ó yẹ kí wọ́n tò láti gbáyé ró àti mú ilé ayé gún Àwọn ètò tó jẹmọ́ ẹ̀sìn Mùsùlùmí ni ìwọ̀nyí; Ẹwà ni ètò tí wọ́n máa ń lò tí láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn ní ẹwà tí ó wà nínú ẹ̀sìn Mùsùlùmí Wọ́n máa ń lo ètò yìí láti kéde fún àwùjọ Wọ́n máa ń lò ó láti sọ àwọn òfin tí ẹ̀sìn yìí máa ń tẹ̀lé tí ayé fi ń gún Wọ́n sì máa ń lò ó láti ran àwọn olùsìn ẹ̀sìn yìí létí nípa òpó márùnún ẹ̀sìn yìí Ètò mìíràn ni Báríkà Jímọ̀ Wọ́n máa ń lo ètò yìí láti kí àwọn aráàlú Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ètò yìí pàtàkì rẹ̀ ni láti kí àwọn ẹlẹ́sìn yìí wọ́n máa ń lu àwo tí ó jẹ́ ti ẹ̀sìn yìí fún ìgbádùn wọn Àwọn lẹ́gbẹ́lẹ́gbẹ́ àti lájọlájọ ni ó máa ń ṣe agbátẹrù àwọn ètò wọ̀nyí láti tan ìhìnrere ẹ̀sìn wọn fún aráyé gbọ́ Àwọn atọ́kùn ètò yìí máa ń jẹ́ ẹni tó mọ ẹ̀sìn yìí dunjú Nígbà mìíràn wọ́n máa ń gbe àlejò wá sórí ètò láti sọ ohun tí ẹ̀sìn yìí fààyè gbà Ipa àwọn ètò yìí ní àwùjọ ni láti tọ́ àwọn ènìyàn sọ́nà tí à fi ń gbáyé tí ayé fi ń gún tí ó sì ń sọ́nà tí à fi ń gbáyé tí ayé fi ń gún tí ó sì ń tòrò nípa fífi Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo àti níní ìbẹ̀rù Ọlọ́run IPA ÀTI ÌWÚLÒ ÈTÒ YORÙBÁ A ó ò wo ipa àti ìwúlò àwọn ètò Yorùbá ní ìbámu pẹ̀lú bí a ṣe ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ètò yìí ní orí kẹ́ta A máa wo ètò àṣà ìṣíde ìròyìn amúlùúdùn àti ẹ̀sìn lọ́kọ̀ọ̀kan ÌṢÍDE Wọ́n máa ń lo ètò ìṣíde láti fi júbà Ọlọ́run Yorùbá gbà wí pé àwọn ní láti máa fi orúkọ Ọlọ́run sí ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe láyé nítorí pé bí kò bá sí Ọlọ́run àbá ẹ̀dá kankan kò le ṣẹ Nítorí náà ìwúlò àkọ́kọ́ tí ètò ìṣíde wà fún ni láti fi Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo tí wọ́n bá fẹ́ ṣe níléiṣẹ́ yìí Nínú ètò ìṣíde yìí wọ́n máa ń wúre nínú rẹ̀ náà Ìwúre yìí wà fún pípe Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo tí wọ́n bá fẹ́ ṣe wọ́n sì máa ń wúre fún àwọn aráàlú àti iléiṣẹ́ yìí Nítorí náà ìwúlò kejì rẹ̀ ni láti fi ṣàdúrà fún àwọn ènìyàn tí ó ń gbọ́ iléiṣẹ́ yìí àti àwọn òṣìṣẹ́ iléiṣẹ́ yìí ÀṢÀ Àtàrí àjànàkú kì í ṣẹrù ọmọdé ni ọ̀rọ̀ nípa àṣà ìṣẹ̀ǹbáyé Yorùbá jẹ́ ìjìnlẹ̀ tí ó ju ẹnu ọmọdé lọ ni Nítorí náà péréte nínú àwọn ọmọ Yorùbá pàápàá jùlọ àwọn tí ò gbé lọ́dọ̀ àgbà ni ó mọ àṣà Yorùbá dunjú Bí a bá kíyèsí lóde òní a ó rí i pé ìmọ̀ nípa àwọn àṣà àti ètò ìbílẹ̀ Yorùbá kúrú púpọ̀ pàápàá láàárín ìlú ńláńlá Yorùbá ti máa ń wí bí kò bá sí ẹ̀sẹ́ kì í ṣẹ́ lásán Ó ní ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ Pàtàkì rẹ̀ ni ẹ̀sìn àti ọ̀làjú àwọn ènìyàn mìíràn tí wọ́n gbà Ṣùgbọ́n iléiṣẹ́ yìí gbé àwọn ètò tí ó jẹ mọ́ àṣà wọ̀nyìí àti láti lè máà jẹ́ kí àwọn àṣà yìí kó lọ sóko ìparun Ìwúlò ètò àṣà ni láti ṣe ìdàgbàsókè àti ìgbélárugẹ àṣà wa pàápàá ìlò èdè Yorùbá Ètò kan wà tí wọ́n ń pè ní agbára mọ̀ọ́n kọ mọ̀ọ́n kà Àwọn tó ṣe agbátẹrù ètò yìí ni àwọn Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè Wọ́n máa ń lo ètò yìí láti sọ àǹfààní tí ó wà nínú èdè wa láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé èdè tí ó gbayì ní àgbáyé ni èdè yìí tí àwọn Òyìnbó aláwọ̀ funfun sì ń wá sílẹ̀ wa láti kọ́ èdè Yorùbá Wọ́n máa ń fi ètò yìí kọ́ wa pé èdè wa jẹ́ nǹkan ìdánimọ̀ àwa ẹ̀yà Yorùbá kí Òyìnbó tó dé ilẹ̀ Yorùbá ni ìran Yorùbá ti wà nílé Ifẹ̀ tí wọ́n sì ń pè é ní ilẹ̀ Odùduwà èyí tí ó túmọ̀ sí pé ilẹ̀ tí ó dá ìwà Ohun tí wọ́n ń fi èyí kọ́ wa ni pé ìran Yorùbá jẹ́ ìran tí ó mú ìwà ọmọlúàbí ní ọ̀kúnkúnkùn Ipa tí ètò àṣà ń kó nínú àwùjọ ni pé ìwà ọmọlúàbí ń gbilẹ̀ ní àwùjọ wa Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìran Yorùbá káràmásìkí ìwà ọmọlúàbí bí i; ẹ̀mí ìranraẹnilọ́wọ́ ìsòtítọ́ ìrẹ̀lẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ àwọn ìwà wọ̀nyí ni wọ́n fi ètò wọ̀nyí kọ́ Ipa mìíràn tí ètò yìí tún kọ́ ni nípa àṣà ìwọṣọ pàápàá láàárín àwọn obìnrin A rí i pé bí wọ́n ṣe ń ṣe ètò tí ó jẹ mọ́ ìwọṣọ tí wọ́n sì ń fọn rere rẹ̀ iyì tí ó wà nínú kí obìnrin daṣọ bo ìhòhò rẹ̀ ni a rí àyípadà rẹ̀ nínú àwùjọ pàápàá èyí tí iléiṣẹ́ yìí wà Bákan náà a rí àṣà wíwọṣọ ìbílẹ̀ wá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aráàlú kì í wọ̀ ọ́ ní ojoojúmọ́ wọ́n a máa wọ̀ ọ́ ní ọjọ́ ẹtì láti gbé àṣà wa lárugẹ ÌRÒYÌN Ní apákan orí kẹ́rin yìí ni a ti o sáájú pé oríṣìí ìròyìn mẹ́ta ni wọ́n máa ń sọ níléiṣẹ́ yìí ìròyìn ní ṣókí ìròyìn lábẹ́lé àti ìròyìn lápapọ̀ Ìwúlò àwọn wọ̀nyí ni láti jábọ̀ ohun tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ nílùú fún àwọn ènìyàn àwùjọ Kì í ṣe jíjábọ̀ ìròyìn nìkan ni iṣẹ́ akàròyìn yóò tún fún ìròyìn yìí ní ìtumọ̀ Wọ́n máa ń fi ìròyìn ta àwọn ènìyàn lólobó nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ Ìwúlò mìíràn ni pé wọ́n máa ń lo ìròyìn láti fi ṣe ìwádìí àwùjọ tàbí àkójọpọ̀ àwùjọ lọ́nà tí aráyé yóò fi gbọ́ tí yóò fi yé wọn Nínú ètò ìròyìn a máa ń rí ìpolówó ọjà níbẹ̀ tàbí ìkéde nínú rẹ̀ Ipa tí àwọn ìkéde tàbí ìpolówó ọjà wọ̀nyí ń kó ni pénípa ètò ọrọ̀ajé iléiṣẹ́ yìí a rí i pé ó máa ń powó wọlé fún wọn Èyí jẹ́ ọ̀nà kan tí iléiṣẹ́ yìí ń gbà láti rí owó tí wọn yóò máa lò fún ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe yàtọ̀ sí èyí tí ìjọba ń fún wọn Yàtọ̀ fún àwọn ìkéde tàbí ìpolówó ọjà tí wọ́n ń ṣe láàárín ìròyìn wọ́n máa ń ní àkókò tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ìkéde tí àwọn ènìyàn sanwó fún Èyí sì jẹ́ ọ̀nà ọrọ̀ajé iléiṣẹ́ yìí tí wọ́n ń gbà powó wọlé Owó tí wọ́n máa ń gbà lórí ìkéde tàbí ìpolówó ọjà kọ̀ọ̀kan dálé orí iye àkókò tí wọ́n bá lò fún un AMÚLÙÚDÙN Nínú àwọn ètò amúlùúdùn tí wọ́n ma ń gbé jáde ní iléeṣẹ́ yìí ni a ti rí ètò bí i; Tíátà Yorùbá Jogbo Àyọkà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ àwọn ètò wọ̀nyí jẹ́ ètò tí ó máa ń kún fún ìlù ijó orin ẹ̀fẹ̀ àti àwàdà Bákan náà a máa ń rí eré amẹ́rìnínwá Ohun tí àwọn ètò yìí wà fún ni igabdun ìgbafẹ́ àti ìdánílarayá àwọn olùgbọ́ Púpọ̀ ètò yìí ni wọ́n gbé kalẹ̀ láti fún ọkàn olùgbọ́ ní ìsinmi yálà lẹ́nu iṣẹ́ tàbí lẹ́yìn gbogbo ìrìnkèrindò òòjọ́ Púpọ̀ àwọn ẹ̀fẹ̀ tàbí àwàdà wọn máa ń dá lé ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ Wọn máa ń ṣe ẹ̀fẹ̀ yìí láti ṣe àfihàn ìwà àwùjọ Ọ̀pọ̀ àwọn èdè tí wọ́n sì máa ń lò kì í jẹ́ èyí tí olùgbọ́ lè tètè gbàgbé Nítorí náà a lè tọ́ka sí pé ipa tí ètò yìí ń kó ní àwùjọ ni pé ó máa ń ṣe àfihàn àwùjọ lọ́nà tí àwọn ènìyàn àwùjọ kò fi ní tètè gbàgbé Ẹ̀SÌN Ètò ẹ̀sìn ní ìwúlò ọlọ́kanòjọ̀kan tí wọ́n máa ń kó Ní iléiṣẹ́ rédíò yìí wọ́n ní àwọn ètò tí wọ́n máa ń ṣe ní ìlànà ẹ̀sìn Mùsùlùmí àti Kìrìsítíẹ́nì Lára àwọn ètò yìí ni a ti rí; Ẹwà Ìrètí Kìrìsítíẹ́nì Obìnrin Oníwà Rere Báriká Jímọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ìwúlò àkọ́kọ́ tí a lè tọ́ka sí ni pé àwọn ètò wọ̀nyí jẹ́ kí á gbàgbọ́ pé Ọlọ́run wà Ọlọ́run sì ni aṣẹ̀dá ohun gbogbo tó wà nílé ayé àti àwa ẹ̀dá ènìyàn Bákan náà àwọn ètò yìí ń tọ́ wa sọ́nà nípa ìlànà tí àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí fẹ́ kí a tẹ̀lé Àwọn ètò wọ̀nyí ń kọ́ wa bí a ṣe lè gbé ìgbé ayé mímọ́ òdodo àti bí a ṣe ń gbé ayé tí ayé fi ń rójú Ipa tí ètò yìí ń kó ní àwùjọ ni pé ó jẹ́ kí á ní ẹ̀mí ìṣọ̀kan níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé àwọn ẹ̀sìn yìí gbàgbọ́ pé Ọlọ́run wà Ọlọ́run yìí sì ni à ń ké sí Òmíràn ni pé ó jẹ́ kí a ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí ní òfin tí wọ́n máa ń tẹ̀lé Èyí sì máa ń jẹ́ kí wọ́n sá fún àwọn ohun tí kò yẹ kí á hù ní ìwà bí i; ìpànìyàn olè jíjà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ẹ̀rù máa ń wà lọ́kàn àwọn ènìyàn nítorí ìjìyà ń bẹ fún ẹni tó bá tàpá sí àwọn òfin wọ̀nyí Tí a bá fi ojú tíọ́rì ìbáraẹnigbépọ̀ ní àwùjọ wo àwọn ipa àti ìwúlò àwọn ètò Yorùbá wọ̀nyí lórí rédíò ìpínlẹ̀ A rí i pé àwọn ètò wọ̀nyí wà fún ìgbádùn ìdárayá ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìtọ́sọ́nà àwọn aráàlú Ajólórí tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì ni àwọn ènìyàn àwùjọ àti ìbáṣepọ̀ wọn àti ipa tí irú ìbáṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ ní lórí àwùjọ Ohun tí ó jẹ tíọ́rì yìí lógún jù ni ìgbà ayé ẹ̀dá nínú àwùjọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ àṣà ìwà àti èdè rẹ̀ èyí tí ó jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ẹ̀dá dúró lé Gbogbo nǹkan tí tíọ́rì yìí fúnka mọ́ ni a rí nínú ipa àti ìwúlò ètò Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ tí ó sì mú kí ìbáṣepọ̀ wà láàárín iléiṣẹ́ yìí àti àwùjọ ÌṢÒRO TÍ ÈTÒ YORÙBÁ Ń KOJÚ LÓRÍ RÉDÍÒ ÌPÍNLẸ̀ Kò sí bí ohun kan ṣe dára tó kó máà ní àléébù rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ṣe tọ́ka sí àwọn ìṣòro ètò náà Bẹ̀rẹ̀ láti orí ìròyìn ní iléiṣẹ́ yìí ìwádìí tí a ṣe lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀ka Yorùbá wọn sọ pé pàtàkì ìṣòro rẹ̀ ni ṣíṣe àtúpalẹ̀ ìròyìn tí àwọn bá gbà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Yorùbá Wọ́n ní ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nígbà mìíràn máa ń pakasọ Bí àpẹẹrẹ wọ́n ní ọ̀rọ̀ mìíràn tí wọ́n bá pè ní èdè Gẹ̀ẹ́sì máa ń nira láti fún ní ìtumọ̀ ní èdè Yorùbá Nígbà mìíràn ìwé atúmọ̀ èdè kì í fún wọn ní ìtumọ̀ tí yóò bá a mu Nítorí náà wọ́n máa ń lọ ìwé atúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì láti fún ní ìtumọ̀ tí yóò bá a mu Àwọn ètò Yorùbá mìíràn wà tí àwọn atọ́kùn rẹ̀ máa ń ṣọ̀wọ́n Wọ́n máa ń wá atọ́kùn kiri ni Kì í ṣe gbogbo ẹni tó le sọ Yorùbá ni ó le è sètò ní Yorùbá Nítorí kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó mọ àpadé àti àludé èdè Yorùbá Ìṣòro mìíràn ni pé wọn kì í rí àwọn onígbọ̀wọ́ fún àwọn ètò Yorùbá Yorùbá ní ìpolówó ọjà làgúnmu òwò Ṣùgbọ́n àwọn onísòwò kì í wá sonígbọ̀wọ́ ètò wọ̀nyí ọ̀pọ̀ àwọn ètò Yorùbá ni ó sì tipaṣẹ̀ èyí parun A lè tọ́ka sí àwọn ọ̀nà àbáyọ mélòó kan àwọn ọ̀nà àbáyọ náà kò sì sòro láti mọ̀ Lára wọn ni; Kí àwọn aráàlú rí iléiṣẹ́ yìí gẹ́gẹ́ bí nǹkan àjọni Kí wọ́n máa rí i gẹ́gẹ́ bí ti ìjọba nìkan Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé kí àwọn aráàlú wá ṣe onígbọ̀wọ́ àwọn ètò wọ̀nyí láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìjọba Àwọn alákòóso iléiṣẹ́ yìí gbọdọ̀ gbìyànjú láti wá ìwé atúmọ̀ èdè tí yóò ran iṣẹ́ ìròyìn títú sí èdè Yorùbá lọ́wọ́ Yàtọ̀ sí èyí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ̀ máa wáyé lóòrèkóòrè fún àwọn akọ̀ròyìn akóròyìnjọ Yorùbá láti mú kí ìmọ̀ wọn tubo gbèrú sí i Ọ̀nà àbáyọ mìíràn ni pé kí wọ́n máa ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí èdè Yorùbá fún àwọn òṣìṣẹ́ wọn lóòrèkóòrè Àbáyọ mìíràn ni pé kí wọ́n wá àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n dáńtọ́ tí wọ́n sì kúnjú òṣùwọ̀n láti máa tukọ̀ àwọn ètò wọ̀nyí Kí àlàáfíà àwọn òṣìṣẹ́ sì jẹ àwọn ìjọba aláṣẹ àti alákòóso lógún kí wọ́n máṣe fi ẹ̀tọ́ wọn dùn wọ́n Irú ìgbésẹ̀ yìí ló le mú ìwúrí bá òṣìṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ láti tẹpá mọ́ṣẹ́ LÁMÈYÍTỌ́ LÓRÍ ÀWỌN ÈTÒ YORÙBÁ Gẹ́gẹ́ bí àlàyé wa ní orí kejì iṣẹ́ yìí a sọ pé tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì ni tíọ́rì ìṣàmúlò wa Tíọ́rì yìí sì fúnka mọ́ ènìyàn àwùjọ àti ìbágbépọ̀ àwọn ènìyàn àwùjọ àti ipa tí irú ìbáṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ ní lórí àwùjọ Ohun tí ó jẹ Soṣíọ́lọ́jì lógún jù ni ìgbéayé ẹ̀dá nínú àwùjọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ àṣà ìwà àti èdè rẹ̀ èyí tí ó jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ẹ̀dá dúró lé Tí a bá wo àwọn ohun tí ó jẹ́ ajólórí tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì a rí pé gbogbo ohun tí ó fúnka mọ́ ni ó wà nínú àwọn ètò wọ̀nyí Bí àpẹẹrẹ nínú ètò tó jẹ mọ́ àṣà a máa ń rí ẹ̀kọ́ ìwà ọmọlúàbí kọ́ nínú ètò tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn a máa ń rí ìgbàgbọ́ awo ènìyàn níbẹ̀ Nínú ètò ìròyìn wọn a rí àwọn kùdìẹ̀kudiẹ mélòó kan níbẹ̀ Ìṣọwọ́loèdè wọn mẹ́hẹ Wọn kì í lo àkọtọ́ òdeòní Bákan náà wọn kì í rí ọ̀rọ̀ tí wọ́n le lò tí yóò bá ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá fẹ́ túmọ̀ láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Yorùbá Ohun tí wọ́n máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ di ọ̀rọ̀ àyálò Ìròyìn tí a bá pè ní ìròyìn àpapọ̀ gbọdọ̀ jẹ́ ìròyìn tí wọ́n yóò ti ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ Èyí ni pé àkókò tí wọ́n gbọdọ̀ máa lò fún ètò ìròyìn yìí gbọdọ̀ ju èyí tí wọ́n ń lò fún ìròyìn ní ṣókí lọ ṣùgbọ́n a rí i pé ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún ni wọ́n ń lò fún ètò yìí èyí ti àwa lérò pé ó yẹ kí wọ́n lè máa lo ọgbọ̀n ìṣẹ́jú fún un láti ṣe ìròyìn yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ní ọ̀pọ̀ ìgbà akàròyìn yìí ni ó máa ń jẹ́ olóòtú ìròyìn èyí tí a lè fi tọ́ka sí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ń fa kùdìẹ̀kudiẹ ètò ìròyìn Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ká fọwọ́ wẹwọ́ lọ́wọ́ fi ń mọ́ Bí olóòtú àti akàròyìn bá yàtọ̀ àwọn méjèèjì yóò jọ fi òye gbé ohun tí ó yẹ kí ó wà nínú ìròyìn náà tàbí ohun tí kò yẹ kí ó wà nínú ròyìn yìí ohun mìíràn tí a tún rí tọ́ka sí nínú ètò ìròyìn wọn ni pé wọ́n máa ń ṣègbè fún àwọn ènìyàn kan ní àwùjọ àti iléiṣẹ́ kan ní àwùjọ Tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì gbà pé oríṣìí ènìyàn méjì ni ó wà nínú àwùjọ; olówó àti mẹ̀kúnnù Ìbáṣepọ̀ tàbí ìbágbépọ̀ tí ó sì fúnka mọ̀ wà láàárín àwọn ènìyàn àwùjọ yìí ṣùgbọ́n nínú ètò ìròyìn wọn a rí i pé àwọn ìròyìn tí ó bá jẹ mọ́ àwọn Gómìnà olówó tàbí iléiṣẹ́ tí ó lórúkọ lórí ni wọ́n máa ń kọ́kọ́ sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìròyìn tí wọn yóò sì sọ tí àwọn mẹ̀kúnnù ní ìparí Ohun tí à ń gbìyànjú láti sọ ni pé tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì kò fààyè gbà pé kí a fi ẹ̀tọ́ àwọn kan dùn wọ́n láti tẹ́ àwọn ará yòókù lọ́rùn déédéé ni ó yẹ kí a pín àwọn ètò náà Kùdìẹ̀kudiẹ tí a rí tọ́ka sí nínú ètò tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn ni pé ní ọjọ́ tí àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí àti Kìrìsítíẹ́nì máa ń lọ jọ́sìn nílé mímọ́ wọn nìkan ni wọ́n máa ń ṣe ètò ẹ̀sìn tí ó jẹ mọ́ ẹ̀sìn wọ̀nyí fún ẹ̀sìn ìbílẹ̀ a rí i pé nínú ìwúre tí wọ́n máa ń ṣe nínú ètò ìṣíde wọn nìkan ni a ti máa ń rí ipa ẹ̀sìn yìí ṣùgbọ́n ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń ṣe ètò yìí Ó yẹ kí wọ́n ní ètò kan gbòógì tí wọ́n yóò máa lò láti fi ṣe ìgbélárugẹ ẹ̀sìn yìí níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wa a sì rí àwọn ènìyàn ní àwùjọ tí wọ́n gbàgbọ́ nínú Jésù Kìrìsítíẹ́nì Aálà Mùsùlùmí àti Ifá ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Nítorí náà ẹ̀sìn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni ó yẹ kí wọ́n máa gbé lárugẹ Ohun tí a lè rí tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí kùdìẹ̀kudiẹ nínú ètò àṣà ni a lè tọ́ka sí nínú ètò tí wọ́n pè ní Àlọ́ o Àlọ́ jẹ́ ọ̀kan nínú eré ìdárayá fún àwọn ọmọdé ní alẹ́ nígbà tí olúkúlùkù bá parí iṣẹ́ rẹ̀ Nígbà náà ni àwọn àgbàlagbà yóò gbé ẹni tí wọn yóò tẹ́ ẹ sí àárín ìta àwọn ọmọdé yóò sí jókòó àwọn àgbà yóò pa àlọ́ fún wọn Àlọ́ àpamọ̀ ń bẹ àlọ́ onítàn sì ń bẹ pẹ̀lú Ìbéèrè ìdáhùn ni àlọ́ àpamọ̀ ṣùgbọ́n àlọ́ onítàn máa ń gùn Ìtàn àròsọ àti àrògún ni àlọ́ onítàn jẹ́ Nígbà tí wọ́n bá sọ ìtàn títí wọn yóò dá orin tí ẹni tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ dá níjọ́un Àwọn ọmọdé yóò máa gbe orin wọn yóò sì máa pàtẹ́wọ́ kí wọ́n sì máa jó Oríṣìí àlọ́ méjèèjì tí a dárúkọ ni wọ́n máa ń pa ní rédíò ṣùgbọ́n àlọ́ onítàn ni wọ́n sábàá máa ń pa jù Ní ayé àtijọ́ àgbàlagbà ni ó máa ń pa àlọ́ fún àwọn ọmọdé ṣùgbọ́n ni rédíò ọ̀dọ́langba ni ẹni tó máa ń ṣe ètò yìí ó le jẹ́ pé atọ́kùn ètò yìí kò tilẹ̀ gbé ọ̀dọ́ àgbà rí tí ó le pa àlọ́ fún tí ó sì jẹ́ pé àwọn àlọ́ tí ó gbọ́ lẹ́nu ẹlòmíràn ni tàbí tí ó kà nínú ìwé Àwọn ọmọdé máa ń jókòó yí agbalaga po ni tàbí kí wọ́n jókòó sí ibi tí àgbà tó ń pa àlọ́ fún wọn bá wà ṣùgbọ́n lórí ètò yìí a kì í gbọ́ ohun àwọn ọmọdé kí wọ́n kópa nínú ètò yìí Ohun tí à ń sọ ni pé ó yẹ kí àwọn ọmọdé máa kópa nínú ètò yìí lórí rédíò kí wọ́n ba à lè ní ìmọ̀lára àlọ́ náà nípa kíkọrin àti pípàtẹ́wọ́ àti dídáhùn ìbéèrè tí ó bá ṣúyọ láàrín ìtàn àlọ́ Tí a bá wo àkókò tí wọ́n ń ṣe ètò yìí lórí rédíò a rí i pé ó bá àkókò tí wọ́n máa ń pààlọ́ ní ilẹ̀ Yorùbá aago méje sí aago méje kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún Tíọ́rì Soṣíọ́lọ́jì fúnka mọ́ ìwà àwọn ènìyàn inú àwùjọ Ohun pàtàkì tí a máa ń fi àlọ́ ṣe ni láti fún àwọn ọmọ ní ìkìlọ̀ ìbáwí àti kọ́ wọn lọ́gbọ́n bí à á ṣe í hùwà Àlọ́ ń jẹ́ kí àwọn ọmọ rí rere tí ó wà nínú rere ṣíṣe àti ibi ṣíṣe yàtọ̀ sí búburú Bákan náà tíọ́rì yìí fúnka mọ́ ìbáṣepọ̀ àwọn ènìyàn àwùjọ Àlọ́ máa ń ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìbáṣepọ̀ àti ẹ̀mí ìranraẹnilọ́wọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ A lè sọ pé ètò Àlọ́ O jẹ́ ètò tí iléeṣẹ́ rédíò ń lò láti gbé àṣà Yorùbá lárugẹ àti láti máa jẹ́ kí àṣà ilẹ̀ wa ó lọ sóko ìparun ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ ÌFÁÀRÀ Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàyé lórí oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ ń gbà gbé èdè Yorùbá lárugẹ pẹ̀lú onírúurú ètò wọn lórí afẹ́fẹ́ ohun tí a ó gbé yẹ̀wò ní abala yìí ni Ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí àmúyẹ àti àléébù ìwádìí yìí àti ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ÌSỌNÍṢÓKÍ ÀBỌ̀ ÌWÁDÌÍ Láìṣe àníàní a ti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ètò Yorùbá àti ní pàtàkì jùlọ ìtàn ìdásílẹ̀ iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ tí ó jẹ́ odò iṣẹ́ ìwádìí yìí A gbìyànjú láti fi rédíò hàn gẹ́gẹ́ bí aṣàwòta àwùjọ àti agbẹnuṣọ fún ìjọba àti aráàlú Nítorí tí ètò rédíò jẹ́ ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí ó pa gbogbo oríṣìíríṣìí ẹ̀yà tó wà ní orílẹ̀èdè yìí pọ̀ ni ó mú kí àǹfààní rédíò fún àwọn aráàlú yàtọ̀ gédégédé sí ti àwọn iléiṣẹ́ ìròyìn yòókù Ní ìpínlẹ̀ láti ọjọ́ tó ti pẹ́ títí di àkókò tí à ń sọ̀rọ̀ yìí iléiṣẹ́ rédíò ni ó dára jù tí wọ́n sì ń gbé ètò jáde ní èdè Yorùbá fún ìlò àwọn ènìyàn àti ìjọba ìpínlẹ̀ náà fún ìpolongo àti ìgbéjáde àwọn ètò mìíràn Èyí ló sì mú kí iléiṣẹ́ náà jẹ́ ọmọlójú fún ìjọba àti àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà Iṣẹ́ àṣekágbá yìí jẹ́ kí á rí ipa pàtàkì tí ètò Yorùbá ń kó ní iléiṣẹ́ rédíò Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìṣòro ni a bá pàdé nípa ká gba ìwádìí sílẹ̀ pàápàá ní àsìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ kò fi bẹ́ẹ̀ ráyè nítorí ètò mìíràn tí wọ́n ń ṣe ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé iṣẹ́ yìí jẹ́ ṣíṣe nígbẹ̀yìn lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àforítì Bákan náà a wo onírúurú ìṣòro tó ń dojúkọ ètò Yorùbá ní iléiṣẹ́ náà pẹ̀lú ọ̀nà abato sí àwọn ìṣòro náà Bí iléiṣẹ́ náà bá fẹ́ kí àyípadà bá àwọn ètò Yorùbá tí wọ́n ń gbé sórí afẹ́fẹ́ wọ́n gbọdọ̀ tètè wá ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìṣòro náà Kí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti àlàáfíà àwọn òṣìṣẹ́ wọn ó sì jẹ́ wọ́n lógún ÀMÚYẸ ÀTI ÀLÉÉBÙ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Iléiṣẹ́ rédíò yìí ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ èdè Yorùbá lílò lórí afẹ́fẹ́ ní ìpínlẹ̀ yìí èyí fi ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n kún ojú òṣùwọ̀n nípa lílo èdè Yorùbá Láti mú kí èdè Yorùbá lórí rédíò ìpínlẹ̀ túbọ̀ làmìlaka sí i yóò dára bí iléiṣẹ́ náà bá tẹ̀lé àwọn ìlànà a tí ṣe àlàkalẹ̀ rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ yìí Gẹ́gẹ́ bí àwọn akọ̀ròyìn èdè Yorùbá nítorí bí akọ̀ròyìn kan bá fetí ara rẹ̀ gbọ́ ìròyìn tí ó sì fojú ara rẹ̀ rí ìṣẹ̀lẹ̀ kan yóò ṣòro láti rí àléébù nínú ìjábọ̀ iṣẹ́ ìròyìn bẹ́ẹ̀ Àtúnkọ ìròyìn bẹ́ẹ̀ fún kíkà lórí afẹ́fẹ́ yóò sì rọrùn Ìdí ni pé títú èdè kan sí òmíràn kò ní ṣàì mú àwọn ìṣòro pẹ́pẹ̀pẹ́ dání Ó yẹ kí iléiṣẹ́ náà ní àpótí ìmọ̀ràn tí ó le máa fún àwọn olùgbọ́ ní àǹfààní láti fi èrò wọn hàn nípa ṣíṣe lámèyítọ́ àwọn ètò tó ń jáde láfẹ́fẹ́ nílé iṣẹ́ náà nípa ṣíṣe báyìí àwọn aláṣẹ yóò lè mọ ibi tí àwọn dára sí àti ohun tí ó jẹ́ àbùkù iléiṣẹ́ náà Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé nípa ìwádìí ni ìlọsíwájú ń gbà bá àwùjọ kan iléiṣẹ́ rédíò ìpínlẹ̀ gbọdọ̀ gbé ìgbìmọ̀ aṣèwádìí kan dìde láì fàsìkò ṣòfò láti túbọ̀ máa ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí bí a ṣe ń gbé ètò sáfẹ́fẹ́ kí àbọ̀ iṣẹ́ ìwádìí wọn sì jẹ́ èyí tó le ran iléiṣẹ́ lọ́wọ́ Iṣẹ́ ṣíṣe lórí rédíò jẹ́ ẹ̀bùn síbẹ̀ iléiṣẹ́ náà gbọdọ̀ gbìyànjú láti rí i dájú pé lẹ́yìn tí àwọn bá gba àwọn òṣìṣẹ́ tó ní ẹ̀bùn tán kí wọ́n fún èyí tó bá yẹ kí ó kàwé sí láàyè láti kàwé lẹ́nu iṣẹ́ èyí tó bá sì nílò ẹ̀kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ kí wọ́n má ṣe fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dùn ún èyí ni ó le mú ìdàgbàsókè àti àyípadà bá akitiyan wọn Ní àfikún iléiṣẹ́ náà gbọdọ̀ kópa nínú àwọn ètò gbogbogbòò àti ìdíje ńlá ńlá bí i ìpàtẹ ọjà àti ìpàdé àpérò ÌMỌ̀RÀN FÚN ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Ọ̀pọ̀ ìṣòro tí a ba pàdé nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún wa pé kò sí ìwé àti ohun èlò tó tó fún iṣẹ́ ìwádìí tó jinlẹ̀ lórí ètò Yorùbá lórí rédíò pàápàá jùlọ àwọn ìwé àkànlò Torí náà aṣèwádìí tó ń bọ̀ lẹ́yìn gbọdọ̀ lè ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀ lórí ètò Yorùbá lórí rédíò Ìmọ̀ràn mi tún lọ sọ́dọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí irú ọpọ́n iṣẹ́ ìwádìí yìí lè sún kàn ní ọjọ́ iwájú pé kí wọ́n fi tọkàn tara ṣe iṣẹ́ ìwádìí yìí kí wọ́n fi ara wọn jìn fún àwọn tí wọ́n ń ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn kí wọ́n máa ṣe rojú owó torí pé arojú owó kì í ṣọ̀ṣọ̀ọ́ kí wọ́n máa ṣe káàárẹ̀ ọ̀kan nítorí pé ẹni tí yóò bá joyin inú àpáta kò ní wo ẹnu àáké Ìmọ̀ràn mi sí àwọn ará iléiṣẹ́ rédíò ìjọba àti iléiṣẹ́ aládàáni pàápàá jùlọ iléiṣẹ́ rédíò ni pé kí wọ́n ní ìmọ̀ nípa bí à á ti polówó ọjà tàbí polongo lọ́nà tí owó yóò fi túbọ̀ máa wọlé fún wọn Nítorí ìpolówó ọjà ni àgúnmu òwò Ìmọ̀ràn mi fún àwọn òṣìṣẹ́ iléiṣẹ́ rédíò ni pé kí wọ́n ma fi ara wọn jìn fún àwọn olùwádìí ìgbà tí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́ wọn Torí pé ọnà kan gbòógì tí ìtẹ̀síwájú lè gbà bá àṣà àti iṣẹ́ Yorùbá ni èyí kí wọ́n sì máa fi òkodoro hàn wọ́n kí wọn mú èrò pé ọ̀nà láti tú àṣírí iṣẹ́ wọn ni ìwádìí dúró lé Bí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ sí àwọn aṣèwádìí èyí yóò fún wọn lóye kíkún lórí ipò tí iṣẹ́ ìròyìn wà bóyá ó ń gòkè àgbà ni tàbí ó dúró rigidi bí adágún odò ÌKÁDÌÍ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní kò sóhun tó ní ìbẹ̀rẹ̀ tí kì í lópin ohun tí í tan lọdún eégún ọmọ alágbaa ń bọ̀ wá ràkàrà fi jẹ̀kọ Bí a bá bọ́jú bọ́mú àgbọ̀n ìsàlẹ̀ là á parí rẹ̀ sí bí ọkọ̀ sì ròkun tó rọ̀ṣà yóò fàbọ̀ sí èbúté Bẹ́ẹ̀ la ò sì ní yàwòrán gàgàrà ká máa fọwọ́ rẹ̀ tí síbì kan èyí ni pé ẹni sọ̀ọ̀rẹ́ èrò mọ́yọ̀ èrò ń relé ẹ̀ bó dọ̀la Ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí mo ṣàlàyé lórí ohun tó gún mi ni kẹ́ṣẹ́ láti ṣe iṣẹ́ yìí bẹ́ẹ̀ ni mo tún sọ ọ̀nà tí ń ó gbé iṣẹ́ ìwádìí yìí gbà Bákan náà mo ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn iṣẹ́ àwọn aṣáájú lórí èdè pàápàá jùlọ àwọn iṣẹ́ àwọn Gẹ̀ẹ́sì tí a túmọ̀ sí èdè Yorùbá Nínú iṣẹ́ yìí náà ni a ti mẹ́nuba rédíò gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ìdìde àti ìdàgbàsókè iléiṣẹ́ rédíò ní Nàìjíríà àti ní ìpínlẹ̀ tí ó jẹ́ odò iṣẹ́ yìí A sọ̀rọ̀ nípa ipa àti ìwúlò ètò Yorùbá lórí iṣẹ́ rédíò àti ìṣòro tí ó kojú àti ọ̀nà àbáyọ fún ìdàgbàsókè èdè Yorùbá ní àwùjọ wa lápapọ̀ ÀKÓJỌPỌ̀ ORÚKỌ ÌWÉ FONỌ́LỌ́JÌ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ AKÍNPẸ̀LÚ ABÍMBỌ́LÁ APÁ KAN IṢẸ́ ÀṢEKÁGBÁ FÚN Ẹ̀KỌ́ ÀKÀGBOYÈ NÍNÚ ÌMỌ̀ ÌPÌLẸ̀ Ẹ̀DÁ NÍNÚ ÈDÈ YORÙBÁ NÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ YUNIFÁSÍTÌ ÌLỌRIN ÌLỌRIN NÀÌJÍRÍÀ OṢÙ IGBE ỌDÚN ÌFỌWỌ́SÍ Iṣẹ́ àkànṣe yìí ni a ti kà tí a sì rí i pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè àti Èdè Nàìjíríà Yunifásítì Ìlọrin Ìlọrin AYA ADÉKẸ́YÈ ỌJỌ́ ALÁBÒÓJÚTÓ OLÙYẸ̀WÒ ÌTA ỌJỌ́ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N ỌJỌ́ OLÓRÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁ ÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ÌFISỌRÍ Mo fi iṣẹ́ àkànṣe yìí sọrí Ọlọ́run ọba Olódùmarè Adẹ́dàá Aṣẹ̀dàá Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo tí ó jẹ́ kí iṣẹ́ àkànṣe yìí jẹ́ àṣeyọrí Bákan náà mo fi sọrí àwọn òbí mi Alàgbà Àbáyọ̀mí àti aya rẹ̀ Ọjẹ́rónkẹ́ Akínpẹ̀lú ÌDÚPẸ́ Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọba alèwílèṣe arúgbó ọjọ́ àríìrọ́ àlá ẹkùn ọkọ òkè ẹ̀bìtì òkè tíí milẹ̀ tìtì ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin ohun gbogbo tí ó mú mi bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí láyọ̀ tí ó sì tún jẹ́ kí mọ parí láyọ̀ Bákan náà mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí mi Alàgbà Àbáyọ̀mí àti aya rẹ̀ Ọjẹ́rónkẹ́ Akínpẹ̀lú fún ìnáwó àti ìnára yín lórí mi láti jẹ́ kí ń kọ́ ẹ̀kọ́ yìí lágbára Ọlọ́run iṣu ọmọ a jinná fún yín jẹ ẹ kò ní fi àárẹ̀ lògbà ẹ ṣé púpọ̀ Ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ alábòójutó iṣẹ́ àṣekágbá yìí aya Adẹ́kẹ́yè mo kí i yín fún ìtọ́sọ́nà àti ìgbani níyànjú yín nígbà gbogbo láti lè mú kí iṣẹ́ àkànṣe yìí kẹ́ṣẹ́ járí lágbára Ọlọ́run gbogbo ìdáwọ́lé yín yóò yọrí sí rere Ọpẹ́ mi lọ sọ́dọ̀ abẹ́nàìmọ̀ mi Alàgbà Gboróyè fún iṣẹ́ takuntakun tí ẹ ṣe fún mi lórí kí iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí lè kẹ́ṣẹ́ járí mo gbàdúrà kí Ọlọ́run kó dúró tì yín àti ìdílé yín Ọpẹ́ mi lọ sọ́dọ̀ Ẹni Ọ̀wọ̀ Olúkáyọ̀dé Ìgè fún àdúrà yín ní gbogbo ìgbà mo gbàdúrà pé àmì òróró yín kò ní gbẹ ẹ ṣeun mo dúpẹ́ Síwájú sí i mọ dúpẹ́ lọ́wọ́ Alàgbà Adépọ̀jù Adédìran fún àtìlẹ́yìn yín ní agbára Ọlọ́run iṣu ọmọ á jinná fún yín jẹ Ọpẹ́ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi Abíọ́lá Akínwùmí Ọlọ́ládé àti fún àtìlẹ́yìn àti àdúrótì yín mo gbàdúrà pé àánú Ọlọ́run a bá a yín kalẹ́ Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Adégúnwà Ọláìtán fún àdúrótì àti àtìlẹ́yìn rẹ Bí ń kò bá dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀gá mi tí ó fi ọgbọ́n ró mi bí aṣọ a jẹ́ wí pé ọpẹ́ mi kò tí ì kún tó nítorí náà mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀gá mi lágbára Ọlọ́run ẹ kò ní ṣiṣẹ́ ṣe Ní ìkádìí mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi Ọláníran Ọláídé Adédèjì Adéníkẹ̀ẹ́ Díẹ̀kọ́lá Ọláníkẹ̀ẹ́ Ọyáwùmí Ọlálékan Owólabí Adéníkẹ̀ẹ́ Ajíbọ́lá Ọlájùmọ̀kẹ́ àti gbogbo àwọn tí ń kò lè dárúkọ ẹ ṣeun mo dúpẹ́ ÀṢAMỌ̀ Ohun tí iṣẹ́ àkànṣe yìí dálé ni ṣíṣe àgbéyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Nínú iṣẹ́ yìí a ó wo èrò àwọn onímọ̀ nípa fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá nípa èdè Yorùbá àti ẹ̀kaèdè Iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò gbìyànjú láti ṣe àfiwé fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá àjùmọ̀lò sí ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A ó sì tún wo àwọn ìyàtọ̀ tó súyọ nínú èdè méjèèjì ÀTẸ ÀKÓÓNÚ Àkọlé Ìfọwọ́sí Ìfisọrí Ìdúpẹ́ Àṣamọ̀ Àtẹ àkóónú ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Ìfáàrà Èrèdí iṣẹ́ ìwádìí yìí Ibi tí ìwádìí gbòròò dé Ọgbọ́n ìwádìí Àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí yìí Ètò ìwádìí ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN Ìfáàrà Èdè Yorùbá Orírun Èdè Àbùdá Èdè Ẹ̀kaÈdè Ẹ̀kaÈdè Ìkálẹ̀ Fònẹ́tíìkì àti Fonọ́lọ́jì Èdè Yorùbá ORÍ KẸ́TA FONỌ́LỌ́JÌ ÈDÈ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ SÍ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ìfáàrà Fonọ́lọ́jì Ẹ̀kaÈdè Ìkálẹ̀ Ìró Kọ́ńsónáǹtì nínú Ẹ̀kaÈdè Ìkálẹ̀ Ìró Fáwẹ́lì nínú Ẹ̀kaÈdè Ìkálẹ̀ Ìró Ohùn nínú Ẹ̀kaÈdè Ìkálẹ̀ ORÍ KẸ́RIN ÀWỌN ÌGBÉSẸ̀ FONỌ́LỌ́JÌ NÍNÚ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ìfáàrà Àrànmọ́ nínú Ẹ̀kaÈdè Ìkálẹ̀ Ìpajẹ Kọ́ńsónáǹtì nínú Ẹ̀kaÈdè Ìkálẹ̀ Ìpajẹ Fáwẹ́lì nínú Ẹ̀kaÈdè Ìkálẹ̀ Àǹkóò Fáwẹ́lì nínú Ẹ̀kaÈdè Ìkálẹ̀ Ìgúnlẹ̀ ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ Ìfáàrà Ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí yìí Àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí yìí Ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú Ìkádìí Àkójọ orúkọ ìwé ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌFÁÀRÀ Yorùbá gẹ́gẹ́ bí èdè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tí ó sì gbajúgbajà káàkiri àgbáyé Fún ìdí èyí kò ní sàìjẹ́ èdè tí à ń ṣiṣẹ́ lé lórí nítorí ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ Kí ó tó di wí pé èdè Yorùbá dé ibi tí ó dé lónìí àwọn onímọ̀ bí i ti ó ṣe iṣẹ́ àkọ́kọ́ lórí àyẹ̀wò àwọn ẹ̀kaèdè ni ó ti ṣe iṣẹ́ takuntakun lórí rẹ̀ Ní báyìí kò jẹ́ ìyálẹ́nu láti sọ wí pé èdè tí a mọ̀ sí Yorùbá jẹ́ eléyìí tí a lè pín sí ẹ̀ka méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ báyìí Yorùbá àjùmọ̀lò àti àwọn ẹ̀kaèdè abẹ́ rẹ̀ Nígbà tí ó ti wá rí báyìí yóò jẹ́ ohun tí ó dára àti ohun àmúyangàn láti mọ ìyàtọ̀ tàbí ìjọra tó wà láàárín ẹ̀kaèdè kan pàtó àti Yorùbá àjùmọ̀lò Fún ìdí èyí ni a ṣe yàn láti ṣe àfiwé fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò láàyò nínú iṣẹ́ yìí ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wí pé oríṣìíríṣìí ni àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá nítorí náà iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì láti mọ èdè Ìkálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa èrèdí iṣẹ́ kan ohun tí à ń sọ ni ohun tí ó ṣe okùnfà irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ Iṣẹ́ mọ́lọ́jì ni láti ṣe ìwádìí lórí ètò àti ìlànà tí ìsẹ̀dá ọ̀rọ̀ ń gbà wáyé nígbà tí iṣẹ́ fonọ́lọ́jì jẹ́ ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró nínú èdè kan pàtó Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí ó ṣe okùnfà iṣẹ́ àkànṣe yìí ni láti wo ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè Yorùbá tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó àti láti mọ ètò ìró wọn Síwájú sí i a wòye pé kò tí ì sí iṣẹ́ ìwádìí kan gbòógì tó dá lórí fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ fún ìdí èyí iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò lè fún wa ní òye kíkún lórí ẹ̀kaèdè náà IBI TÍ ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ Kò sí bí ìwádìí ṣe lè gbòòrò tó tí kò ní ní ibi tí yóò mọ Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò sọ fún wa onírúurú ìyànjú tí àwọn onímọ̀ ti ṣe nípa fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá Lára àwọn nǹkan tó jẹ olùwádìí lógún jùlọ ni láti ṣe fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá ohun tí èdè Yorùbá ganan jẹ́ ẹ̀kaèdè àti ètò ìró ní ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí náà ni a ó ti wo ìpilẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí èrèdí iṣẹ́ ìwádìí yìí bákan náà a ó wo àgbéyẹ̀wò aáyan ọ̀mọ̀ràn A ó tún ṣe àfiwé fóníìmù èdè Yorùbá nínú Yorùbá àjùmọ̀lò sí ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ a ó tún wo àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Lákòótán a ó tún wo àmúyẹ iṣẹ́ náà a ó sì dá ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ ọ̀la ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ Oríṣìíríṣìí ọgbọ́n ìwádìí ló wà ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a mú lò nínú wọn Lára àwọn èyí ti a múlò ni wọ̀nyí lílo àtòjọ ìbéèrè ìlànà yìí máa ń ran oníṣẹ́ ìwádìí lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìbéèrè tí yóò bí abẹ́nàìmọ̀ rẹ̀ Lílọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́nàìmọ̀ èyí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ọgbọ́n ìwádìí tí ó wà lílọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́nàìmọ̀ yìí yóò ran olùwádìí lọ́wọ́ àti lè ṣe ìwádìí tómúná dóko lórí iṣẹ́ rẹ̀ Síwájú sí i lílo ìlànà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ibí yìí ni a ti lo ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀ láti fi gba ohùn abẹ́nàìmọ̀ sílẹ̀ láti fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ìbéèrè tí a bi abẹ́nàìmọ̀ Ní àkótán a ṣe àmúlò ìmọ̀ inú ìwé Àwọn ìmọ̀ yìí ni ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyanjú ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Oríṣìíríṣìí ni àǹfààní tí iṣẹ́ ìwádìí yìí lè mú bá ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá àti gírámà èdè Yorùbá àti fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá lápapọ̀ Iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò jẹ́ kí a ní ìmọ̀ tó kún nípa fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò wúlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ iwájú tí wọ́n fẹ́ ṣe ìwádìí lórí àkọlé tí ó farapẹ́ èyí àti láti sọ ìwúlò fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá Ní àkótán tí a bá wo fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá a ó rí i wí pé oríṣìí ìlànà àti ìgbésẹ̀ ni ó ní àwọn ìlànà àti ìgbésẹ̀ bí i àrànmọ́ ìpàrójẹ pẹ̀lú àwọn ìlànà yìí yóò tún ṣe wá ní àǹfààní láti fi lè wo fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ lákọ̀tun ÈTÒ ÌWÁDÌÍ Èròǹgbà iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti ṣe iṣẹ́ lórí fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A pín iṣẹ́ ìwádìí yìí sí orí márùnún tí a sì ṣe ìfáàrà lórí ohun tí ó pilẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí Nínú rẹ̀ ni a ó ti sọ èrèdí iṣẹ́ ìwádìí yìí ibi tí ìwádìí yóò gbòòrò dé ọgbọ́n ìwádìí àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí àti ètò rẹ̀ Nínú orí kejì ni a ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò lórí Aáyan ọ̀mọ̀ràn bákan náà ni a tún ṣe àgbéyẹ̀wò lórí fonọ́lọ́jì àti fònẹ́tíìkì èdè Yorùbá Orí kẹ́ta ni a ó ti sọ̀rọ̀ nípa àfiwé fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ìfáàrà ni ó bẹ̀rẹ̀ orí yìí a ó sì wo àwọn ètò ìró nínú ẹ̀kaèdè náà Ní orí kẹ́rin ni a ti máa wo àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Orí karùnún ni a ti ṣe àgbálọgbábọ̀ ibẹ̀ ni a ó ti wo àmúyẹ lẹ́yìn eléyìí a ó wo ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN ÌFÁÀRÀ Nínú orí yìí ni a ti sọ̀rọ̀ lórí ohun tí èdè jẹ́ ẹ̀kaèdè ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti fònẹ́tíìkì àti fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá Ohun tí ó bá ní ètò tí ó ní ìtumọ̀ tí a sì lè fi ìró gbé jáde ni a mọ̀ sí èdè A sì tún mọ̀ pẹ̀lú pé ara èdè ni a ti rí ẹ̀kaèdè Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró nínú èdè kan pàtó bákan náà nínú fònẹ́tíìkì ni a ti mọ bí a ṣe ń gbé ìró jáde tí ó fi ń di ẹyọ ọ̀rọ̀ Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni a fẹ́ gbé yẹ̀wò nínú orí yìí ÈDÈ YORÙBÁ Èdè jẹ́ ohun ìní ènìyàn nìkan àwùjọ tàbí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ló ní èdè tirẹ̀ Ìdí nìyí tí a fi máa ń sọ pé èdè Yorùbá Haúsá Ìgbò Gẹ̀ẹ́sì Faransé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Oríkì tí a lè fún èdè pọ̀ A lè sọ pé èdè ni ohun tí ó ní ètò àti ìtumọ̀ tí a sì fi ìró èdè gbé jáde Lójú àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè èdè jẹ́ ohun tí ó mú kí àwọn ènìyàn ní àjọsepọ̀ láàárín ara wọn ó sì tún ń mú kí ìròyìn ó máa dé etígbọ̀ọ́ wọn Onímọ̀ kan tí a mọ̀ sí sọ pé Èyí túmọ̀ sí; Èdè kì í ṣe ọ̀nà à ti máa bára ẹni sọ̀rọ̀ fún ìròyìn nípa àkókò tàbí ohun mìíràn bí kò ṣe ọ̀nà láti máa bára ẹni gbépọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn Onímọ̀ mìíràn ni Èyí túmọ̀ sí; Èdè ni batani tí a fi ètò ìró ìhun tí ó jẹ́ àtinúdá ènìyàn tí a sọ pọ̀ mọ́ ìṣẹ̀ṣe tí a sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀dá ènìyàn Ọ̀kan nínú àwọn tó ṣe pàtàkì jùlọ láàárín àwọn ọmọ adáríhurun ni èdè ọ̀rọ̀ sísọ àti bíbá ara ẹni sọ̀rọ̀ Èdè ni ohun tí ó ní agbára jùlọ tí a fi máa ń bára ẹni sọ̀rọ̀ ORÍRUN ÈDÈ Ní èrò àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè tàbí onímọ̀ lìngúísíìkì a kò lè ṣo ní pàtó bí èdè ṣe bẹ̀rẹ̀ Kò sí ẹni lè sọ báwo ìgbà wo tàbí ìlànà wo ni èdè gbà bẹ̀rẹ̀ Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípa ìhùwàsí àwọn ẹranko àti ènìyàn kò tí ì rí ojútùú rẹ̀ títí di àsìkò yìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí wọn kò dúró Ó fẹ́rẹ̀ dàbí pé ìmọ̀ nípa ẹ̀sìn àti ìfojúẹ̀sìnwoèdè ni a lè sọ pé ó gbìyànjú díẹ̀ láti gbé èrò nípa orírun èdè yọ Olówóòkéré ṣe àgbékalẹ̀ ohun tí ó kà nípa orirun èdè nínú ìwé Maya tí a ń pè ní pé lẹ́yìn tí Ẹlẹ́dàá dá ohun gbogbo nǹkan tán ló dá àwa ènìyàn láti sọ̀rọ̀ Ó sì fún àwọn ènìyàn ní agbára láti fún èdè yòókù ní orúkọ Wọ́n gbà nínú ìtàn iwase wọ́n pé àwọn ẹranko náà ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi èrò inú wọn hàn ṣùgbọ́n akitiyan láti ní èdè wọn já sí òtubáńtẹ́ Ó ṣe é ṣe kó jẹ́ pé olú ìmísí àbí ìwádìí tí àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè ṣe nìyí tí wọ́n fi sọ pé èdè jẹ́ ohun àdámọ́ ÀBÙDÁ ÈDÈ Àbùdá èdè ni ó máa ń jẹ́ kí a mọ ohun tí èdè jẹ́ ganan oríṣìíríṣìí ni àwọn àbùdá èdè ni Ohun tí a bá pè ní èdè gbọdọ̀ jẹ́ ohun tí a fi ìró èdè gbé jáde Ìró yìí ni a lè pè ní ariwo tí a fi ẹnu pa Èdè nílò kíkọ́ fún ìgbà pípẹ́ díẹ̀ kí ènìyàn tó lè sọ ọ́ Gbogbo èdè kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ìró èdè tirẹ̀ tí à ń pè ní fóníìmù Èdè ọmọ ènìyàn ni ó ṣe é ṣe ohun tí ó bá wà ní ayika wa àti ohun tí ó bá ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ Èdè àwa ẹ̀dá máa ń ní bátànì èyí ni pé ó ní bí àwọn ọ̀rọ̀ ṣe ń papọ̀ pẹ̀lú láti fún wa ní ọ̀rọ̀ Èdè ni a fi fa ẹwà yọ nínú afọ̀ Ẹ̀KAÈDÈ Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wí pé láti ara èdè ni ẹ̀kaẹ̀dá ti jáde ó yẹ kí a mọ ohun tí èdè jẹ kí a tó lè máa sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kaèdè Èdè ni ohun tí ó ní ètò tí ó sì ní ìtumọ̀ tí a sì fi ìró èdè gbé jáde Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni Yorùbá ti ní orúkọ àjùmọ́jẹ́ ti gbogbo ọmọ ilẹ̀ káàárọ̀oòjíire ń pe ara wọn àti èdè wọn ní ayé òde òní Àmọ́ báyìí kọ́ ni nǹkan rí tẹ́lẹ̀ Tẹ́lẹ̀ rí àdúgbò tàbí ẹkùn kọ̀ọ̀kan ni ó ní orúkọ ara rẹ̀ kò sì sí orúkọ kankan gúnmọ́ fún gbogbo wọn àti èdè wọn lápapọ̀ Irú àwọn orúkọ tí ó wà fún ẹkùn kọ̀ọ̀kan nìwọ̀nyí Ìṣẹ́kìrí Ànàgó Ìgalà Akú Ìjẹ̀bú Ọ̀yọ́ Èkìtì Iyàgbà Owé Ẹ̀gbá Ìkálẹ̀ Oǹdó Ifẹ̀ Ọ̀wọ̀ Àkókó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ọ̀nà méjì ni a lè pín àwọn orúkọ tí a kàjọ sókè yìí sí Èkííní jẹ́ ti àwọn tí a o ó pè ní ẹ̀yà èdè Àwọn wọ̀nyí jẹ́ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó bá èdè Yorùbá tan irú àwọn èdè yìí pọ̀ wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò fi lè dárúkọ gbogbo wọn tán Àwọn tí ọ̀nà kejì ni a lè pè ní ẹ̀kaèdè A rí i wí pé àwọn tí ó ń sọ àwọn ẹ̀kaèdè gbogbo wọ́n pọ̀ju àwọn tí ó ń sọ ẹ̀yà ẹ̀kaèdè lọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí àwọn kan nínú wọ́n ṣe máa ń sọ ọ́ lẹ́nu yàtọ̀ sí bí àwọn mìíràn ṣe máa ń sọ ọ́ síbẹ̀ wọn kò ní orúkọ àjùmọ̀jẹ́ kan pàtó fún wọn èdè náà Ó ṣe pàtàkì fún wa láti mọ̀ pé èdè kan kò dára ju ekeji lọ ìbáse èdè Faransé tàbí Fùfúdè Ìgalà tàbí Èbìrà Yorùbá tàbí Ìgbò èdè ni èdè Iṣẹ́ tí èdè kan sì ń ṣe láàárín àwọn tó ń sọ náà ni èdè mìíràn ń ṣe Ó ṣòro láti sọ ní pàtó iye ẹ̀kaèdè tí ó wà nínú èdè Yorùbá ìdí ni pé àwọn ẹ̀yàẹ̀ka pọ̀ nínú àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá Orílẹ̀èdè Nàìjíríà nìkan kọ́ ni a ti ń sọ Yorùbá Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ìkálẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú ọmọ bíbí Odùduwà Odùduwà jẹ́ ọmọ Lámúrúdu Lámúrúdu jẹ́ ọmọ Égíbítì Odùduwà bí ọmọ mẹ́rìndínlógún nínú àwọn ọmọ yìí ọ̀kan nínú wọn ń jẹ́ Monikeneyin Monikeneyin lọ ṣe aṣíwájú ọba Ìkálẹ̀ Ọba Monikeneyin jẹ́ ọdẹ òun ló sì bí Ìkálẹ̀ àti Ìlàjẹ Lẹ́yìn ikú ọba Monikeneyin yìí ni àwọn ọmọ ọba méjèèjì; Ìkálẹ̀ àti Ìlàjẹ wá yapa tí Ìkálẹ̀ dá dúró lọ́tọ̀ tí Ìlàjẹ náà dúró lọ́tọ̀ Níbẹ̀ ni a ti rí Ìkálẹ̀ mẹ́sànán Lára àwọn Ìkálẹ̀ mẹ́sànán náà ni a ti rí; Aye Èrìnjẹ̀ Ayéka Ìrèlè Àjàgbà àti ÒdeÒmì FÒNẸ́TÍÌKÌ ÀTI FONỌ́LỌ́JÌ Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró inú èdè kan pàtó nínú olórí ẹ̀kaèdè tí a mọ̀ sí Yorùbá àjùmọ̀lò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìró ni a lè pè jáde láti inú ẹnu ìró ni ó ń so pọ̀ di ọ̀rọ̀ tí ọ̀rọ̀ sì di àpólà tí àpólà yìí wá di gbólóhùn fún ìbánisọ̀rọ̀ Adéfilá sọ pé Gbígbé ìró jáde dá lórí ìfọwọ́ṣowọ́pọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí ó jẹ́ kí ìró di gbígbé jáde Táíwò ki fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá báyìí; Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa ìṣàpéjúwe àwọn ìró ìfọ̀ nínú èdè àti bátànì tí àwọn ìróìfọ̀ nínú èdè Fònẹ́tíìkì ń ṣe ìwádìí lórí àbùdá àti ìhun ìró nípa ìlànà mẹ́ta Ọ̀nà kìíní ni àgbéjáde nípasẹ̀ ìṣẹnupè èkéjì ni àbùdá nípasẹ̀ ìfetígbọ́ àti ẹ̀kẹ́ta tí ó jẹ́ àbùdá nípa ìgbọ́àfẹ̀rọwò Àwọn ìlànà tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni àkọ́kọ́ àti ẹ̀kẹ́ta Fònẹ́tíìkì ìṣẹnupè ni ìwádìí bí a ṣe ń gbé ìró jáde láti káà ẹnu Lára àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí à ń lò láti gbé ìró jáde ni ẹ̀dọ̀fóró tánánná àlàfo tánánná gògòńgò imú ètè ẹnu ahọ́n eyín Bákan náà bí àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ wọ̀nyí ṣe ń bá ara wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ láti gbé ìró jáde wà lọ́wọ́ ìró tí a bá pè A ní àfipè àsúnsí àti `afipè àkànmọ́lẹ̀ Lára àwọn àfipè àkànmọ́lẹ̀ ni a ti rí; èrìgì àjàẹnu àfàsé ètè òkè Àpẹẹrẹ àfipè àsúnsí ni a ti rí ètè ìsàlẹ̀ àti ahọ́n Lọ́nà kan sá a lè sọ pé ẹ̀kọ́ nípa onírúurú ìró tí àwọn ènìyàn ń pè jáde nígbà tí a bá ń fọ̀ kí a ṣe àpèjúwe àwọn ìró náà kí a sì pín wọn sí ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí a sì tún ṣàlàyé nípa fáwẹ́lì kọ́ńsónáǹtì àti ohùn inú èdè ni fònẹ́tíìkì jẹ́ nígbà tí ẹ̀kọ́ nípa irú ìró fi ìyàtọ̀ hàn nínú èdè àti ìbátan tí ó wà láàárín àwọn ìró tí ó fi ìyàtọ̀ hàn nínú ọ̀rọ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí kò lè fi ìyàtọ̀ hàn àti bátànì tí à ń lò fún wọn lábẹ́ ohun tí à ń pè ní fonọ́lọ́jì ni a ti ń kọ́ irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ORÍ KẸ́TA FONỌ́LỌ́JÌ ÈDÈ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ SÍ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌFÁÀRÀ Ohun tí a fẹ́ gbéyẹ̀wò nínú orí yìí ni àfiwé fonọ́lọ́jì Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ní orí yìí kan náà ni a ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì àti fáwẹ́lì tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ohun tí ó máa gbẹ̀yìn orí yìí ni àwọn ìró ohùn tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti èyí tí a rí nínú olórí ẹ̀kaèdè Yorùbá FONỌ́LỌ́JÌ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa fonọ́lọ́jì inú èdè kan ohun tí à ń gbìyànjú láti sọ náà ni àbùdá àdáni ìró nínú èdè yẹn pàtó Nínú abala yìí ni a tí máa wo àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì inú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ìró kọ́ńsónáǹtì ni a máa ń pè nígbà tí ìdíwọ́ bá wà fún èémí tí ó ń bọ̀ láti inú ẹ̀dọ̀fóró àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì tí a ní nínú èdè Yorùbá nìwọ̀nyí Bákan náà ìró tí a pè nígbà tí kò sí ìdíwọ́ fún èémí tí ó ń bọ̀ láti inú ẹ̀dọ̀fóró ni ìró fáwẹ́lì Àwọn ìró fáwẹ́lì tí ó wà nínú èdè Yorùbá nìwọ̀myí Nínú orí yìí bákan náà ni a ti máa wo ìró ohùn tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ìró ohùn mẹ́ta; ìró ohùn òkè ìró ohùn àárín àti ìró ohùn ìsàlẹ̀ tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni ó wà nínú àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ÌRÓ KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ NÍNÚ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ohun tí a ó yẹ̀wò níbi yìí ni àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì tí a lè rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé nínú àwọn ìró tí a lè bá pàdé nínú Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe pàtàkì kí a ṣe àlàyé tó múná dóko lórí ìró kọ́ńsónáǹtì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A rí àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì wọ̀nyí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ni Àtẹ ìsàlẹ̀ yìí ṣàlàyé ní kíkún lórí kọ́ńsónáǹtì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ÀTẸ KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ọ̀NÀ ÌṢẸNUPÈ Afètèpè Àfeyínfètèpè Afèrìgìpè Afàjàafèrìgìpè Afàjàpè Afafàsépè Afafàsétèpè Àfitánánnápè Tí a bá wo àwọn àpèjúwe yìí àti àpẹẹrẹ kọ̀ọ̀kan lábẹ́ àwọn ìró kọ̀ọ̀kan a rí wí pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ nínú ìró kọ́ńsónáǹtì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò ṣùgbọ́n àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì kan wà tí kò sí nínú Yorùbá àjùmọ̀lò tí ó sì wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró bí i gh gw bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìró kan wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò tí kò sí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ bí i ∫ j y Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀ ní ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì kan wà tí wọ́n fi ń rọ́pọ̀ ara wọn àwọn ìró bí i w fún gh s fún h ÌRÓ FÁWẸ́LÌ NÍNÚ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ohun tí a ó yẹ̀wò níbí yìí ni àwọn ìró fáwẹ́lì tí a lè rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé nínú àwọn ìró tí a lè pàdé nínú Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe pàtàkì kí a ṣe àlàyé tó múná dóko lórí ìró fáwẹ́lì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A rí àwọn ìró fáwẹ́lì wọ̀nyí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ni i e ẹ a u o Àtẹ ìsàlẹ̀ yìí ṣàlàyé kíkún nípa àwọn fáwẹ́lì wọ̀nyí ÀWỌN ÌGBÉSẸ̀ FONỌ́LỌ́JÌ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌFÁÀRÀ Nínú orí yìí ni a ti máa wo àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tí ó jẹyọ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì bí i àrànmọ́ àti oríṣìí àrànmọ́ tí ó wà ìpàrójẹ́ ìpajẹ fáwẹ́lì àti ìpajẹ kọ́ńṣónáǹtì àǹkóò fáwẹ́lì ÀRÀNMỌ́ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Nínú abala yìí ohùn tí fẹ́ gbé yẹ̀wò náà ni àrànmọ́ tó súyọ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn oríṣìí àrànmọ́ tí a fẹ́ gbé yẹ̀wò náà ni àrànmọ́ iwájú àrànmọ́ ẹ̀yìn àrànmọ́ aláìfòró àrànmọ́ afòró ṣùgbọ́n ki a tó tẹ̀síwájú ó yẹ ki a mọ ohùn tí àrànmọ́ jẹ́ Gẹ́gẹ́ bí Oyèbádé ti ki àrànmọ́ ó ní; Ohùn tì onímọ̀ yìí ń gbìyànjú láti sọ náà ni wí pé nígbà tí ìró méjì tí ó jẹ́ nǹkankan náà tàbí tí ó yàtọ̀ si ara wọn bá dí ìró kan pé àrànmọ́ ti wáyé nìyẹn Ó tún wà tẹ̀síwájú nínú àlàyé tí o ń ṣe lórí àrànmọ́ ó ní ÌGÚNLẸ̀ Tí a bà wo ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ìyàtọ̀ díẹ̀ náà ló wà nínú bí a ṣe ń pé àwọn ọ̀rọ̀ kan Ohùn tí ó tún fẹ́ jẹ́ ìyàtọ̀ ni pé àwọn kọ́ńsónáǹtì kan wà ti kò sí nínú Yorùbá àjùmọ̀lò ti ó sì wà ni ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn kọ́ńṣónáǹtì bí i gh àti gw Bàkan náà kò sì kọ́ńṣónáǹtì ∫ nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ tí ó sì wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò Ìró fáwẹ́lì tí ó sì wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni ó wà ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ohùn mìíràn tí ó jẹ ìyàtọ̀ tó fẹ́ wà láàárín ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni wí pé ní ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ wọ́n máa ń fi fáwẹ́lì u bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn bí àpẹẹrẹ ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ ÌFÁÀRÀ Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wi pé orí ti ó gbẹ̀yìn iṣẹ́ ìwádìí yìí ni a dé yìí Nínú orí yìí ni a ó ti ṣe àgbálọgbábọ̀ gbogbo ohun tí a ń sọ bọ̀ lórí iṣẹ́ àkànṣe yìí Nínú orí yìí ni a ó ṣe ìsọnísókí àbajáde ìwádìí àmúyẹ àti ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ÌSONÍSÓKÍ ÀBỌ̀ ÌWÁDÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wi pé ohun tí iṣẹ́ àkànṣe yìí dálé ni fonọ́lọ́jì ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ tí a si ṣe àfiwé rẹ̀ pẹ̀lú Yorùbá àjùmọ̀lò nínú orí mẹrin tí iṣẹ́ yìí pin si Láti Ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ni ó ti farahàn pé ipò pàtàkì ni fonọ́lọ́jì wà láàárín gírámà èdè ní àgbáyé tí kò si yọ èdè Yorùbá sílẹ̀ náà ni a ṣe ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí fonọ́lọ́jì jẹ́ Gẹ́gẹ́ bí a ti kí fonọ́lọ́jì aní fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa ìsàpèjúwa àwọn ìróifọ̀ nínú èdè àti bátànì tí àwọn ìróifọ̀ ní nínú èdè bàkan náà a tun ki fònẹ́tíìkì torí pé àti fonọ́lọ́jì àti fònẹ́tíìkì àwọn méjèèjì ń bá ara wọ́n ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ gírámà A wo ohun ti èdè jẹ́ orírun èdè àbùdá èdè A si tun wo ohun ti ẹ̀ka èdè jẹ́ fún ra rẹ̀ àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ nítorí pé fonọ́lọ́jì ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ ni a ṣe Bákan náà a wo àwọn ìró tí a lè bà pàdé nínú ẹ̀dáèdè Ìkálẹ̀ èyí ni àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì ìró fáwẹ́lì àti ìró ohùn A yẹ àwọn ìgbèsẹ̀ fonọ́lọ́jì ti a lè rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì bí i àrànmọ́ ìpàrójẹ́ ti a si wo ìyàtọ̀ tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ tí a si ṣe ìgínlẹ̀ lórí gbogbo rẹ̀ ÀMÚYẸ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé kò sí bí iṣẹ́ kan ṣe lè wà tí kò ní ní àwọn àmúyẹ kan tàbí òmíràn Lára àwọn àmúyẹ inú iṣẹ́ yìí ni pé ó mú kí a ní ìmọ̀ tó dájú nípa ìlú Ìkálẹ̀ ti ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ìpínlẹ̀ Òndó ó tun jẹ́ ki a mọ bí àwọn Ìkálẹ̀ ṣe ń pé ìró àti bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn ìró jáde Ohùn mìíràn tí ó tun ṣe pàtàkì ni pé ó jẹ́ ki a mọ àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà nínú àwọn ìró kan nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò o sí tun jẹ́ kí a mọ iye ìró kọ́ńṣónáǹtì àti ìró fáwẹ́lì tí ó wà nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ ó jẹ́ ki a mọ̀ wí pé ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ wà lára àwọn ẹ̀kaèdè tí wọ́n ní fáwẹ́lì àìránmúpè méje tí fáwẹ́lì u si lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn Lákòtán ó jẹ́ ki á mọ̀ ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè Yorùbá tí ó ṣe pàtàkì tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè tí ó gbájugbajà láàárín ilẹ̀ Yorùbá ÌMỌ̀RÀN FÚN ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé iṣẹ́ àkànṣe yìí dálé fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ìmọ̀ràn mi fún oníṣẹ́ ìwádìí ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ìpele gírámà tí ó wà àwọn ìpele gírámà bí i mọfọ́lọ́jì síntáàsì oníṣẹ́ ìwádìí le ṣiṣẹ́ lórí àwọn wọ̀nyí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ tàbí nínú ẹ̀kaèdè mìíràn ÌKÁDÌÍ A ti gbìyànjú láti ṣe àgbéyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ nígbà tí a ti mọ ohun tí fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá jẹ́ èdè Yorùbá àti ẹ̀kaèdè tí a sì ti yẹ àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ wò Bákan náà a rí i wí pé ọ̀kan lára ẹ̀ka èdè Yorùbá tí a kò lè fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ni ẹ̀kaèdè yìí jẹ́ nínú èdè Yorùbá ÀKÓJỌ ORÚKỌ ÌWÉ Yorùbá Àjàyí Ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá Ẹ̀dáÈdè Lítíréṣọ̀ àti Àṣà IjebuOde Sebiotimọ Awóbùlúyì Yorùbá Èdè Ìperí Yorùbá Ìbàdàn Bámgbóṣé A Èdè Ìperí Yorùbá Bámgbóṣé A Fonọ́lọ́jì àti Gírámà Yorùbá Ìbàdàn Odùyẹmí SO Àfiwé Fonọ́lọ́jì Ẹ̀kaÈdè Akúrẹ́ àti Yorùbá Àjùmọ̀lò Iṣẹ́ Àṣekágbá Fún Gbígba Oyè Bíi Eè Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè àti Èdè Ilẹ̀ Nàìjíríà Ìlọrin Olúnládé T Èdè Yorùbá àti Ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè Fọlá Oyèbádé F IjebuOde Sebiotimo Oyè T Mọ́lọ́jì ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌFÁÀRÀ Yorùbá gẹ́gẹ́ bí èdè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tí ó sì gbajúgbajà káàkiri àgbáyé Fún ìdí èyí kò ní sàìjẹ́ èdè tí à ń ṣiṣẹ́ lé lórí nítorí ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ Kí ó tó di wí pé èdè Yorùbá dé ibi tí ó dé lónìí àwọn onímọ̀ bí i ti ó ṣe iṣẹ́ àkọ́kọ́ lórí àyẹ̀wò àwọn ẹ̀kaèdè ni ó ti ṣe iṣẹ́ takuntakun lórí rẹ̀ Ní báyìí kò jẹ́ ìyálẹ́nu láti sọ wí pé èdè tí a mọ̀ sí Yorùbá jẹ́ eléyìí tí a lè pín sí ẹ̀ka méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ báyìí Yorùbá àjùmọ̀lò àti àwọn ẹ̀kaèdè abẹ́ rẹ̀ Nígbà tí ó ti wá rí báyìí yóò jẹ́ ohun tí ó dára àti ohun àmúyangàn láti mọ ìyàtọ̀ tàbí ìjọra tó wà láàárín ẹ̀kaèdè kan pàtó àti Yorùbá àjùmọ̀lò Fún ìdí èyí ni a ṣe yàn láti ṣe àfiwé fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò láàyò nínú iṣẹ́ yìí ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wí pé oríṣìíríṣìí ni àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá nítorí náà iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì láti mọ èdè Ìkálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa èrèdí iṣẹ́ kan ohun tí à ń sọ ni ohun tí ó ṣe okùnfà irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ Iṣẹ́ mọ́lọ́jì ni láti ṣe ìwádìí lórí ètò àti ìlànà tí ìsẹ̀dá ọ̀rọ̀ ń gbà wáyé nígbà tí iṣẹ́ fonọ́lọ́jì jẹ́ ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró nínú èdè kan pàtó Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí ó ṣe okùnfà iṣẹ́ àkànṣe yìí ni láti wo ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè Yorùbá tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó àti láti mọ ètò ìró wọn Síwájú sí i a wòye pé kò tí ì sí iṣẹ́ ìwádìí kan gbòógì tó dá lórí fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ fún ìdí èyí iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò lè fún wa ní òye kíkún lórí ẹ̀kaèdè náà IBI TÍ ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ Kò sí bí ìwádìí ṣe lè gbòòrò tó tí kò ní ní ibi tí yóò mọ Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò sọ fún wa onírúurú ìyànjú tí àwọn onímọ̀ ti ṣe nípa fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá Lára àwọn nǹkan tó jẹ olùwádìí lógún jùlọ ni láti ṣe fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá ohun tí èdè Yorùbá ganan jẹ́ ẹ̀kaèdè àti ètò ìró ní ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí náà ni a ó ti wo ìpilẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí èrèdí iṣẹ́ ìwádìí yìí bákan náà a ó wo àgbéyẹ̀wò aáyan ọ̀mọ̀ràn A ó tún ṣe àfiwé fóníìmù èdè Yorùbá nínú Yorùbá àjùmọ̀lò sí ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ a ó tún wo àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Lákòótán a ó tún wo àmúyẹ iṣẹ́ náà a ó sì dá ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ ọ̀la ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ Oríṣìíríṣìí ọgbọ́n ìwádìí ló wà ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a mú lò nínú wọn Lára àwọn èyí ti a múlò ni wọ̀nyí lílo àtòjọ ìbéèrè ìlànà yìí máa ń ran oníṣẹ́ ìwádìí lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìbéèrè tí yóò bí abẹ́nàìmọ̀ rẹ̀ Lílọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́nàìmọ̀ èyí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ọgbọ́n ìwádìí tí ó wà lílọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́nàìmọ̀ yìí yóò ran olùwádìí lọ́wọ́ àti lè ṣe ìwádìí tómúná dóko lórí iṣẹ́ rẹ̀ Síwájú sí i lílo ìlànà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ibí yìí ni a ti lo ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀ láti fi gba ohùn abẹ́nàìmọ̀ sílẹ̀ láti fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ìbéèrè tí a bi abẹ́nàìmọ̀ Ní àkótán a ṣe àmúlò ìmọ̀ inú ìwé Àwọn ìmọ̀ yìí ni ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyanjú ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Oríṣìíríṣìí ni àǹfààní tí iṣẹ́ ìwádìí yìí lè mú bá ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá àti gírámà èdè Yorùbá àti fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá lápapọ̀ Iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò jẹ́ kí a ní ìmọ̀ tó kún nípa fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò wúlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ iwájú tí wọ́n fẹ́ ṣe ìwádìí lórí àkọlé tí ó farapẹ́ èyí àti láti sọ ìwúlò fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá Ní àkótán tí a bá wo fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá a ó rí i wí pé oríṣìí ìlànà àti ìgbésẹ̀ ni ó ní àwọn ìlànà àti ìgbésẹ̀ bí i àrànmọ́ ìpàrójẹ pẹ̀lú àwọn ìlànà yìí yóò tún ṣe wá ní àǹfààní láti fi lè wo fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ lákọ̀tun ÈTÒ ÌWÁDÌÍ Èròǹgbà iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti ṣe iṣẹ́ lórí fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A pín iṣẹ́ ìwádìí yìí sí orí márùnún tí a sì ṣe ìfáàrà lórí ohun tí ó pilẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí Nínú rẹ̀ ni a ó ti sọ èrèdí iṣẹ́ ìwádìí yìí ibi tí ìwádìí yóò gbòòrò dé ọgbọ́n ìwádìí àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí àti ètò rẹ̀ Nínú orí kejì ni a ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò lórí Aáyan ọ̀mọ̀ràn bákan náà ni a tún ṣe àgbéyẹ̀wò lórí fonọ́lọ́jì àti fònẹ́tíìkì èdè Yorùbá Orí kẹ́ta ni a ó ti sọ̀rọ̀ nípa àfiwé fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ìfáàrà ni ó bẹ̀rẹ̀ orí yìí a ó sì wo àwọn ètò ìró nínú ẹ̀kaèdè náà Ní orí kẹ́rin ni a ti máa wo àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Orí karùnún ni a ti ṣe àgbálọgbábọ̀ ibẹ̀ ni a ó ti wo àmúyẹ lẹ́yìn eléyìí a ó wo ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN ÌFÁÀRÀ Nínú orí yìí ni a ti sọ̀rọ̀ lórí ohun tí èdè jẹ́ ẹ̀kaèdè ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti fònẹ́tíìkì àti fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá Ohun tí ó bá ní ètò tí ó ní ìtumọ̀ tí a sì lè fi ìró gbé jáde ni a mọ̀ sí èdè A sì tún mọ̀ pẹ̀lú pé ara èdè ni a ti rí ẹ̀kaèdè Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró nínú èdè kan pàtó bákan náà nínú fònẹ́tíìkì ni a ti mọ bí a ṣe ń gbé ìró jáde tí ó fi ń di ẹyọ ọ̀rọ̀ Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni a fẹ́ gbé yẹ̀wò nínú orí yìí ÈDÈ YORÙBÁ Èdè jẹ́ ohun ìní ènìyàn nìkan àwùjọ tàbí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ló ní èdè tirẹ̀ Ìdí nìyí tí a fi máa ń sọ pé èdè Yorùbá Haúsá Ìgbò Gẹ̀ẹ́sì Faransé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Oríkì tí a lè fún èdè pọ̀ A lè sọ pé èdè ni ohun tí ó ní ètò àti ìtumọ̀ tí a sì fi ìró èdè gbé jáde Lójú àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè èdè jẹ́ ohun tí ó mú kí àwọn ènìyàn ní àjọsepọ̀ láàárín ara wọn ó sì tún ń mú kí ìròyìn ó máa dé etígbọ̀ọ́ wọn Onímọ̀ kan tí a mọ̀ sí sọ pé Èyí túmọ̀ sí; Èdè kì í ṣe ọ̀nà à ti máa bára ẹni sọ̀rọ̀ fún ìròyìn nípa àkókò tàbí ohun mìíràn bí kò ṣe ọ̀nà láti máa bára ẹni gbépọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn Onímọ̀ mìíràn ni ó ní; Èyí túmọ̀ sí; Èdè ni batani tí a fi ètò ìró ìhun tí ó jẹ́ àtinúdá ènìyàn tí a sọ pọ̀ mọ́ ìṣẹ̀ṣe tí a sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀dá ènìyàn Ọ̀kan nínú àwọn tó ṣe pàtàkì jùlọ láàárín àwọn ọmọ adáríhurun ni èdè ọ̀rọ̀ sísọ àti bíbá ara ẹni sọ̀rọ̀ Èdè ni ohun tí ó ní agbára jùlọ tí a fi máa ń bára ẹni sọ̀rọ̀ ORÍRUN ÈDÈ Ní èrò àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè tàbí onímọ̀ lìngúísíìkì a kò lè ṣo ní pàtó bí èdè ṣe bẹ̀rẹ̀ Kò sí ẹni lè sọ báwo ìgbà wo tàbí ìlànà wo ni èdè gbà bẹ̀rẹ̀ Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípa ìhùwàsí àwọn ẹranko àti ènìyàn kò tí ì rí ojútùú rẹ̀ títí di àsìkò yìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí wọn kò dúró Ó fẹ́rẹ̀ dàbí pé ìmọ̀ nípa ẹ̀sìn àti ìfojúẹ̀sìnwoèdè ni a lè sọ pé ó gbìyànjú díẹ̀ láti gbé èrò nípa orírun èdè yọ Olówóòkéré ṣe àgbékalẹ̀ ohun tí ó kà nípa orirun èdè nínú ìwé Maya tí a ń pè ní pé lẹ́yìn tí Ẹlẹ́dàá dá ohun gbogbo nǹkan tán ló dá àwa ènìyàn láti sọ̀rọ̀ Ó sì fún àwọn ènìyàn ní agbára láti fún èdè yòókù ní orúkọ Wọ́n gbà nínú ìtàn iwase wọ́n pé àwọn ẹranko náà ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi èrò inú wọn hàn ṣùgbọ́n akitiyan láti ní èdè wọn já sí òtubáńtẹ́ Ó ṣe é ṣe kó jẹ́ pé olú ìmísí àbí ìwádìí tí àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè ṣe nìyí tí wọ́n fi sọ pé èdè jẹ́ ohun àdámọ́ ÀBÙDÁ ÈDÈ Àbùdá èdè ni ó máa ń jẹ́ kí a mọ ohun tí èdè jẹ́ ganan oríṣìíríṣìí ni àwọn àbùdá èdè ni Ohun tí a bá pè ní èdè gbọdọ̀ jẹ́ ohun tí a fi ìró èdè gbé jáde Ìró yìí ni a lè pè ní ariwo tí a fi ẹnu pa Èdè nílò kíkọ́ fún ìgbà pípẹ́ díẹ̀ kí ènìyàn tó lè sọ ọ́ Gbogbo èdè kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ìró èdè tirẹ̀ tí à ń pè ní fóníìmù Èdè ọmọ ènìyàn ni ó ṣe é ṣe ohun tí ó bá wà ní ayika wa àti ohun tí ó bá ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ Èdè àwa ẹ̀dá máa ń ní bátànì èyí ni pé ó ní bí àwọn ọ̀rọ̀ ṣe ń papọ̀ pẹ̀lú láti fún wa ní ọ̀rọ̀ Èdè ni a fi fa ẹwà yọ nínú afọ̀ Ẹ̀KAÈDÈ Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wí pé láti ara èdè ni ẹ̀kaẹ̀dá ti jáde ó yẹ kí a mọ ohun tí èdè jẹ kí a tó lè máa sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kaèdè Èdè ni ohun tí ó ní ètò tí ó sì ní ìtumọ̀ tí a sì fi ìró èdè gbé jáde Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni Yorùbá ti ní orúkọ àjùmọ́jẹ́ ti gbogbo ọmọ ilẹ̀ káàárọ̀oòjíire ń pe ara wọn àti èdè wọn ní ayé òde òní Àmọ́ báyìí kọ́ ni nǹkan rí tẹ́lẹ̀ Tẹ́lẹ̀ rí àdúgbò tàbí ẹkùn kọ̀ọ̀kan ni ó ní orúkọ ara rẹ̀ kò sì sí orúkọ kankan gúnmọ́ fún gbogbo wọn àti èdè wọn lápapọ̀ Irú àwọn orúkọ tí ó wà fún ẹkùn kọ̀ọ̀kan nìwọ̀nyí Ìṣẹ́kìrí Ànàgó Ìgalà Akú Ìjẹ̀bú Ọ̀yọ́ Èkìtì Iyàgbà Owé Ẹ̀gbá Ìkálẹ̀ Oǹdó Ifẹ̀ Ọ̀wọ̀ Àkókó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ọ̀nà méjì ni a lè pín àwọn orúkọ tí a kàjọ sókè yìí sí Èkííní jẹ́ ti àwọn tí a o ó pè ní ẹ̀yà èdè Àwọn wọ̀nyí jẹ́ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó bá èdè Yorùbá tan irú àwọn èdè yìí pọ̀ wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò fi lè dárúkọ gbogbo wọn tán Àwọn tí ọ̀nà kejì ni a lè pè ní ẹ̀kaèdè A rí i wí pé àwọn tí ó ń sọ àwọn ẹ̀kaèdè gbogbo wọ́n pọ̀ju àwọn tí ó ń sọ ẹ̀yà ẹ̀kaèdè lọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí àwọn kan nínú wọ́n ṣe máa ń sọ ọ́ lẹ́nu yàtọ̀ sí bí àwọn mìíràn ṣe máa ń sọ ọ́ síbẹ̀ wọn kò ní orúkọ àjùmọ̀jẹ́ kan pàtó fún wọn èdè náà Ó ṣe pàtàkì fún wa láti mọ̀ pé èdè kan kò dára ju ekeji lọ ìbáse èdè Faransé tàbí Fùfúdè Ìgalà tàbí Èbìrà Yorùbá tàbí Ìgbò èdè ni èdè Iṣẹ́ tí èdè kan sì ń ṣe láàárín àwọn tó ń sọ náà ni èdè mìíràn ń ṣe Ó ṣòro láti sọ ní pàtó iye ẹ̀kaèdè tí ó wà nínú èdè Yorùbá ìdí ni pé àwọn ẹ̀yàẹ̀ka pọ̀ nínú àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá Orílẹ̀èdè Nàìjíríà nìkan kọ́ ni a ti ń sọ Yorùbá Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ìkálẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú ọmọ bíbí Odùduwà Odùduwà jẹ́ ọmọ Lámúrúdu Lámúrúdu jẹ́ ọmọ Égíbítì Odùduwà bí ọmọ mẹ́rìndínlógún nínú àwọn ọmọ yìí ọ̀kan nínú wọn ń jẹ́ Monikeneyin Monikeneyin lọ ṣe aṣíwájú ọba Ìkálẹ̀ Ọba Monikeneyin jẹ́ ọdẹ òun ló sì bí Ìkálẹ̀ àti Ìlàjẹ Lẹ́yìn ikú ọba Monikeneyin yìí ni àwọn ọmọ ọba méjèèjì; Ìkálẹ̀ àti Ìlàjẹ wá yapa tí Ìkálẹ̀ dá dúró lọ́tọ̀ tí Ìlàjẹ náà dúró lọ́tọ̀ Níbẹ̀ ni a ti rí Ìkálẹ̀ mẹ́sànán Lára àwọn Ìkálẹ̀ mẹ́sànán náà ni a ti rí; Aye Èrìnjẹ̀ Ayéka Ìrèlè Àjàgbà àti Òde Òmì FÒNẸ́TÍÌKÌ ÀTI FONỌ́LỌ́JÌ Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró inú èdè kan pàtó nínú olórí ẹ̀kaèdè tí a mọ̀ sí Yorùbá àjùmọ̀lò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìró ni a lè pè jáde láti inú ẹnu ìró ni ó ń so pọ̀ di ọ̀rọ̀ tí ọ̀rọ̀ sì di àpólà tí àpólà yìí wá di gbólóhùn fún ìbánisọ̀rọ̀ Adéfilá sọ pé Gbígbé ìró jáde dá lórí ìfọwọ́ṣowọ́pọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí ó jẹ́ kí ìró di gbígbé jáde Táíwò ki fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá báyìí; Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa ìṣàpéjúwe àwọn ìró ìfọ̀ nínú èdè àti bátànì tí àwọn ìróìfọ̀ nínú èdè Fònẹ́tíìkì ń ṣe ìwádìí lórí àbùdá àti ìhun ìró nípa ìlànà mẹ́ta Ọ̀nà kìíní ni àgbéjáde nípasẹ̀ ìṣẹnupè èkéjì ni àbùdá nípasẹ̀ ìfetígbọ́ àti ẹ̀kẹ́ta tí ó jẹ́ àbùdá nípa ìgbọ́àfẹ̀rọwò Àwọn ìlànà tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni àkọ́kọ́ àti ẹ̀kẹ́ta Fònẹ́tíìkì ìṣẹnupè ni ìwádìí bí a ṣe ń gbé ìró jáde láti káà ẹnu Lára àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí à ń lò láti gbé ìró jáde ni ẹ̀dọ̀fóró tánánná àlàfo tánánná gògòńgò imú ètè ẹnu ahọ́n eyín Bákan náà bí àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ wọ̀nyí ṣe ń bá ara wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ láti gbé ìró jáde wà lọ́wọ́ ìró tí a bá pè A ní àfipè àsúnsí àti `afipè àkànmọ́lẹ̀ Lára àwọn àfipè àkànmọ́lẹ̀ ni a ti rí; èrìgì àjàẹnu àfàsé ètè òkè Àpẹẹrẹ àfipè àsúnsí ni a ti rí ètè ìsàlẹ̀ àti ahọ́n Lọ́nà kan sá a lè sọ pé ẹ̀kọ́ nípa onírúurú ìró tí àwọn ènìyàn ń pè jáde nígbà tí a bá ń fọ̀ kí a ṣe àpèjúwe àwọn ìró náà kí a sì pín wọn sí ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí a sì tún ṣàlàyé nípa fáwẹ́lì kọ́ńsónáǹtì àti ohùn inú èdè ni fònẹ́tíìkì jẹ́ nígbà tí ẹ̀kọ́ nípa irú ìró fi ìyàtọ̀ hàn nínú èdè àti ìbátan tí ó wà láàárín àwọn ìró tí ó fi ìyàtọ̀ hàn nínú ọ̀rọ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí kò lè fi ìyàtọ̀ hàn àti bátànì tí à ń lò fún wọn lábẹ́ ohun tí à ń pè ní fonọ́lọ́jì ni a ti ń kọ́ irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ORÍ KẸ́TA FONỌ́LỌ́JÌ ÈDÈ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ SÍ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌFÁÀRÀ Ohun tí a fẹ́ gbéyẹ̀wò nínú orí yìí ni àfiwé fonọ́lọ́jì Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ní orí yìí kan náà ni a ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì àti fáwẹ́lì tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ohun tí ó máa gbẹ̀yìn orí yìí ni àwọn ìró ohùn tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti èyí tí a rí nínú olórí ẹ̀kaèdè Yorùbá FONỌ́LỌ́JÌ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa fonọ́lọ́jì inú èdè kan ohun tí à ń gbìyànjú láti sọ náà ni àbùdá àdáni ìró nínú èdè yẹn pàtó Nínú abala yìí ni a tí máa wo àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì inú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ìró kọ́ńsónáǹtì ni a máa ń pè nígbà tí ìdíwọ́ bá wà fún èémí tí ó ń bọ̀ láti inú ẹ̀dọ̀fóró àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì tí a ní nínú èdè Yorùbá nìwọ̀nyí Bákan náà ìró tí a pè nígbà tí kò sí ìdíwọ́ fún èémí tí ó ń bọ̀ láti inú ẹ̀dọ̀fóró ni ìró fáwẹ́lì Àwọn ìró fáwẹ́lì tí ó wà nínú èdè Yorùbá nìwọ̀myí a e ẹ i o ọ u Nínú orí yìí bákan náà ni a ti máa wo ìró ohùn tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ìró ohùn mẹ́ta; ìró ohùn òkè ìró ohùn àárín àti ìró ohùn ìsàlẹ̀ tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni ó wà nínú àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ÌRÓ KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ NÍNÚ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ohun tí a ó yẹ̀wò níbi yìí ni àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì tí a lè rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé nínú àwọn ìró tí a lè bá pàdé nínú Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe pàtàkì kí a ṣe àlàyé tó múná dóko lórí ìró kọ́ńsónáǹtì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A rí àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì wọ̀nyí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ni Àtẹ ìsàlẹ̀ yìí ṣàlàyé ní kíkún lórí kọ́ńsónáǹtì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ÀTẸ KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ọ̀NÀ ÌṢẸNUPÈ Afètèpè Àfeyínfètèpè Afèrìgìpè Afàjàafèrìgìpè Afàjàpè Afafàsépè Afafàsétèpè Àfitánánnápè Tí a bá wo àwọn àpèjúwe yìí àti àpẹẹrẹ kọ̀ọ̀kan lábẹ́ àwọn ìró kọ̀ọ̀kan a rí wí pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ nínú ìró kọ́ńsónáǹtì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò ṣùgbọ́n àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì kan wà tí kò sí nínú Yorùbá àjùmọ̀lò tí ó sì wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró bí i gh gw bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìró kan wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò tí kò sí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ bí Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀ ní ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì kan wà tí wọ́n fi ń rọ́pọ̀ ara wọn àwọn ìró bí i w fún gh s fún h ÌRÓ FÁWẸ́LÌ NÍNÚ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ohun tí a ó yẹ̀wò níbí yìí ni àwọn ìró fáwẹ́lì tí a lè rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé nínú àwọn ìró tí a lè pàdé nínú Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe pàtàkì kí a ṣe àlàyé tó múná dóko lórí ìró fáwẹ́lì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A rí àwọn ìró fáwẹ́lì wọ̀nyí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ni i e ẹ a u o ọ Àtẹ ìsàlẹ̀ yìí ṣàlàyé kíkún nípa àwọn fáwẹ́lì wọ̀nyí ÀTẸ FÁWẸ́LÌ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ kó fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ nínú àwọn ìró fáwẹ́lì tí ó wà ni Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè ìkálẹ̀ pípè àti gbígbé àwọn ìró náà jade nìkan nì ó fi ìyàtọ̀ hàn Nínú ẹ̀kaèdè ìkálẹ̀ wọ́n sábà máa ń fi àwọn ìró kan rọpò ara wọn nígbà mìíràn bí àpẹẹrẹ ìró bí i i fún a bí àpẹẹrẹ ÌRÓ OHÙN NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Oríṣìí ìró ohùn mẹ́ta tí ó wà ní Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni ó wà nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró ohùn wọ̀nyí Ìró ohùn òkè i Ìró ohùn àárín Ìró ohùn ìsàlẹ̀ ÌRÓ OHÙN OKE NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Bí ìró ohùn òkè kò tìlè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀ yìí fihàn pé ìró ohùn òkè kò lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ni ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ÌRÓ OHÙN ÀÁRÍN NÍNÚ Ẹ̀DÁ ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Bí ìró ohùn àárín ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò náà nì ó lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ à ti pé kò sí ibi tí kò tí lè jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ Bí àpẹẹrẹ ÌRÓ OHÙN ÌSÀLẸ̀ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Bí ìró ohùn ìsàlẹ̀ ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ní Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà nì ó ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ Ìró ohùn ìsàlẹ̀ sì lè jeyọ ni ìpòkípò nínú ọ̀rọ̀ ìyẹn ní ìbẹ̀rẹ̀ àárín àti ìparí ọ̀rọ̀ Bí àpẹẹrẹ ÌJẸYỌPỌ̀ OHÙN NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Oríṣìí ẹ̀yà ohùn mẹ́tẹ̀ta ni wọ́n ní àǹfààní láti jẹyọ pẹ̀lú ara wọn kó dà nínú ọ̀rọ̀ onísílébù mèjì OHÙN ÌSÀLẸ̀ OHÙN ÒKÈ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ OHÙN ÀÁRÍN OHÙN ÒKÈ OHÙN ÀÁRÍN OHÙN ÀÁRÍN ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ irin orin epo OHÙN ÌSÀLẸ̀ OHÙN ÀÁRÍN ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ẹsẹ̀ nǹkan ìwo òni OHÙN ÌSÀLẸ̀ OHÙN ÌSÀLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ òsì ata ọ̀rọ̀ sìn mọ̀ Ohùn métẹ̀ta náà lè jẹjọ papọ̀ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń jeyọ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò OHÙN ÒKÈ OHÙN ÀÁRÍN OHÙN ÌSÀLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ fowọ̀kàn yípadà dápadà fàmọ́ra ORÍ KẸ́RIN ÀWỌN ÌGBÉSẸ̀ FONỌ́LỌ́JÌ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌFÁÀRÀ Nínú orí yìí ni a ti máa wo àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tí ó jẹyọ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì bí i àrànmọ́ àti oríṣìí àrànmọ́ tí ó wà ìpàrójẹ́ ìpajẹ fáwẹ́lì àti ìpajẹ kọ́ńṣónáǹtì àǹkóò fáwẹ́lì ÀRÀNMỌ́ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Nínú abala yìí ohùn tí fẹ́ gbé yẹ̀wò náà ni àrànmọ́ tó súyọ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn oríṣìí àrànmọ́ tí a fẹ́ gbé yẹ̀wò náà ni àrànmọ́ iwájú àrànmọ́ ẹ̀yìn àrànmọ́ aláìfòró àrànmọ́ afòró ṣùgbọ́n ki a tó tẹ̀síwájú ó yẹ ki a mọ ohùn tí àrànmọ́ jẹ́ Gẹ́gẹ́ bí Oyèbádé ti ki àrànmọ́ ó ní; Ohùn tì onímọ̀ yìí ń gbìyànjú láti sọ náà ni wí pé nígbà tí ìró méjì tí ó jẹ́ nǹkankan náà tàbí tí ó yàtọ̀ si ara wọn bá dí ìró kan pé àrànmọ́ ti wáyé nìyẹn Ó tún wà tẹ̀síwájú nínú àlàyé tí o ń ṣe lórí àrànmọ́ ó ní Ohùn tí onímọ̀ yìí ń gbìyànjú láti sọ láti òkè náà ni pé ìró afàrànmọ̀ wà ìró agbàrànmọ̀ sì wà pẹ̀lú A lè wo bí àrànmọ́ ṣe rìn láti sọ irú àrànmọ́ tó wáyé ÀRÀNMỌ́WÁJÚ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÌPAJẸ FÁWẸ́LÌ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìpajẹ fáwẹ́lì nínú èdè kan èyí máa ń wáyé nígbà tí fáwẹ́lì méjì bá fì ẹgbẹ̀kẹ̀gbẹ̀ ni àlàfo ọ̀rọ̀ Èyí túmọ̀ sí pé fáwẹ́lì lo gbọdọ̀ parí ọ̀rọ̀ àkókò tí fáwẹ́lì sì gbọdọ̀ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ kejì Nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ fáwẹ́lì ọ̀rọ̀iṣẹ́ ti ó jẹ́ àìránmípè nìkan ni a sábà máa ń pajẹ tí a sì máa ń dá ti ọ̀rọ̀ orúkọ sí ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ta ẹja teja teja he ọbe hobè sebè lo ose losẹ lose he epo hepo sepo lo ọkọ lọkọ lukọ ÀNKÓÒ FÁWẸ́LÌ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ fáwẹ́lì àìránmúpè méje ni wọ́n ni tí fáwẹ́lì u sì lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn A lè pín ànkóò fáwẹ́lì ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ si ọ̀wọ́ méjì báyìí Ọ́wọ́ Òwọ́ i u ẹ ọ e o a Àpẹẹrẹ ànkóò fáwẹ́lì ọ̀wọ́ nínú ìkaèdè Ìkálẹ̀ Ọ̀WỌ́ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ efifi èéfún erúrú éérú usu iṣu okuta ọlọ èdúdú èédú ibé ibí koro jí muko fún ulé ilé origho orí ùlú ìlú ohì òsì Àpẹẹrẹ ànkóò fáwẹ́lì ọ̀wọ́ nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ Ọ̀WỌ́ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ẹhẹ̀ ẹsẹ̀ ahọ àwọ̀ ọ̀fọ̀ ọ̀rọ̀ ọma ọmọ ọ̀nẹ ọ̀ni káwá wá kálọ lọ afẹ́fẹ́ ìjì ọlọ́dẹ ọdẹ ẹgba ọrẹ́ Nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ẹ̀wẹ̀ àwọn fáwẹ́lì ọ̀rọ̀ méjéèjì lè bá ara wọn siṣẹ́ nínú ọ̀rọ̀ Òwọ̀ àti ọ̀wọ́ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ erun ẹnu ìgban àgbọ̀n uràgbọ̀n irùngbọ̀n ẹyan ọmú ughọ ìdodo hejijẹ oúnjẹ iwin ìgbé uná iná udabo àdá urọ́ irọ́ ÌGÚNLẸ̀ Tí a bà wo ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ìyàtọ̀ díẹ̀ náà ló wà nínú bí a ṣe ń pé àwọn ọ̀rọ̀ kan Ohùn tí ó tún fẹ́ jẹ́ ìyàtọ̀ ni pé àwọn kọ́ńsónáǹtì kan wà ti kò sí nínú Yorùbá àjùmọ̀lò ti ó sì wà ni ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn kọ́ńṣónáǹtì bí i gh àti gw Bàkan náà kò sì kọ́ńṣónáǹtì ∫ nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ tí ó sì wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò Ìró fáwẹ́lì tí ó sì wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni ó wà ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ohùn mìíràn tí ó jẹ ìyàtọ̀ tó fẹ́ wà láàárín ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni wí pé ní ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ wọ́n máa ń fi fáwẹ́lì u bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn bí àpẹẹrẹ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ usu iṣu uku ikèn ughọ ìdodo urọ́ irọ́ utan ìtan Bákan náà wọ́n tún máa ń lo kọ́ńṣónáǹtì h fún s bí àpẹẹrẹ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ehè ẹsẹ̀ òhì òsì hùn sùn háré séré họn ekun sunkún ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ ÌFÁÀRÀ Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wi pé orí ti ó gbẹ̀yìn iṣẹ́ ìwádìí yìí ni a dé yìí Nínú orí yìí ni a ó ti ṣe àgbálọgbábọ̀ gbogbo ohun tí a ń sọ bọ̀ lórí iṣẹ́ àkànṣe yìí Nínú orí yìí ni a ó ṣe ìsọnísókí àbajáde ìwádìí àmúyẹ àti ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ÌSONÍSÓKÍ ÀBỌ̀ ÌWÁDÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wi pé ohun tí iṣẹ́ àkànṣe yìí dálé ni fonọ́lọ́jì ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ tí a si ṣe àfiwé rẹ̀ pẹ̀lú Yorùbá àjùmọ̀lò nínú orí mẹrin tí iṣẹ́ yìí pin si Láti Ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ni ó ti farahàn pé ipò pàtàkì ni fonọ́lọ́jì wà láàárín gírámà èdè ní àgbáyé tí kò si yọ èdè Yorùbá sílẹ̀ náà ni a ṣe ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí fonọ́lọ́jì jẹ́ Gẹ́gẹ́ bí a ti kí fonọ́lọ́jì aní fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa ìsàpèjúwa àwọn ìróifọ̀ nínú èdè àti bátànì tí àwọn ìróifọ̀ ní nínú èdè bàkan náà a tun ki fònẹ́tíìkì torí pé àti fonọ́lọ́jì àti fònẹ́tíìkì àwọn méjèèjì ń bá ara wọ́n ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ gírámà A wo ohun ti èdè jẹ́ orírun èdè àbùdá èdè A si tun wo ohun ti ẹ̀ka èdè jẹ́ fún ra rẹ̀ àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ nítorí pé fonọ́lọ́jì ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ ni a ṣe Bákan náà a wo àwọn ìró tí a lè bà pàdé nínú ẹ̀dáèdè Ìkálẹ̀ èyí ni àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì ìró fáwẹ́lì àti ìró ohùn A yẹ àwọn ìgbèsẹ̀ fonọ́lọ́jì ti a lè rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì bí i àrànmọ́ ìpàrójẹ́ ti a si wo ìyàtọ̀ tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ tí a si ṣe ìgínlẹ̀ lórí gbogbo rẹ̀ ÀMÚYẸ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé kò sí bí iṣẹ́ kan ṣe lè wà tí kò ní ní àwọn àmúyẹ kan tàbí òmíràn Lára àwọn àmúyẹ inú iṣẹ́ yìí ni pé ó mú kí a ní ìmọ̀ tó dájú nípa ìlú Ìkálẹ̀ ti ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ìpínlẹ̀ Òndó ó tun jẹ́ ki a mọ bí àwọn Ìkálẹ̀ ṣe ń pé ìró àti bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn ìró jáde Ohùn mìíràn tí ó tun ṣe pàtàkì ni pé ó jẹ́ ki a mọ àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà nínú àwọn ìró kan nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò o sí tun jẹ́ kí a mọ iye ìró kọ́ńṣónáǹtì àti ìró fáwẹ́lì tí ó wà nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ ó jẹ́ ki a mọ̀ wí pé ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ wà lára àwọn ẹ̀kaèdè tí wọ́n ní fáwẹ́lì àìránmúpè méje tí fáwẹ́lì u si lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn Lákòtán ó jẹ́ ki á mọ̀ ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè Yorùbá tí ó ṣe pàtàkì tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè tí ó gbájugbajà láàárín ilẹ̀ Yorùbá ÌMỌ̀RÀN FÚN ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé iṣẹ́ àkànṣe yìí dálé fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ìmọ̀ràn mi fún oníṣẹ́ ìwádìí ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ìpele gírámà tí ó wà àwọn ìpele gírámà bí i mọfọ́lọ́jì síntáàsì oníṣẹ́ ìwádìí le ṣiṣẹ́ lórí àwọn wọ̀nyí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ tàbí nínú ẹ̀kaèdè mìíràn ÌKÁDÌÍ A ti gbìyànjú láti ṣe àgbéyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ nígbà tí a ti mọ ohun tí fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá jẹ́ èdè Yorùbá àti ẹ̀kaèdè tí a sì ti yẹ àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ wò Bákan náà a rí i wí pé ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè Yorùbá tí a kò lè fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ni ẹ̀kaèdè yìí jẹ́ nínú èdè Yorùbá ÀKÓJỌ ORÚKỌ ÌWÉ Yorùbá Language Àjàyí Ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá Ẹ̀dáÈdè Lítíréṣọ̀ àti Àṣà IjebuOde Sebiotimọ Awóbùlúyì Yorùbá Èdè Ìperí Yorùbá Ìbàdàn Bámgbóṣé A ed Yorùbá Èdè Ìperí Yorùbá Bámgbóṣé A Fonọ́lọ́jì àti Gírámà Yorùbá Ìbàdàn Odùyẹmí SO Àfiwé Fonọ́lọ́jì Ẹ̀kaÈdè Akúrẹ́ àti Yorùbá Àjùmọ̀lò Iṣẹ́ Àṣekágbá Fún Gbígba Oyè Bíi Eè Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè àti Èdè Ilẹ̀ Nàìjíríà Ìlọrin Olúnládé T Èdè Yorùbá àti Ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè Fọlá Oyèbádé F IjebuOde Sebiotimo Oyè T Mọ́lọ́jì ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌFÁÀRÀ Yorùbá gẹ́gẹ́ bí èdè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tí ó sì gbajúgbajà káàkiri àgbáyé Fún ìdí èyí kò ní sàìjẹ́ èdè tí à ń ṣiṣẹ́ lé lórí nítorí ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ Kí ó tó di wí pé èdè Yorùbá dé ibi tí ó dé lónìí àwọn onímọ̀ bí i ti ó ṣe iṣẹ́ àkọ́kọ́ lórí àyẹ̀wò àwọn ẹ̀kaèdè ni ó ti ṣe iṣẹ́ takuntakun lórí rẹ̀ Ní báyìí kò jẹ́ ìyálẹ́nu láti sọ wí pé èdè tí a mọ̀ sí Yorùbá jẹ́ eléyìí tí a lè pín sí ẹ̀ka méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ báyìí Yorùbá àjùmọ̀lò àti àwọn ẹ̀kaèdè abẹ́ rẹ̀ Nígbà tí ó ti wá rí báyìí yóò jẹ́ ohun tí ó dára àti ohun àmúyangàn láti mọ ìyàtọ̀ tàbí ìjọra tó wà láàárín ẹ̀kaèdè kan pàtó àti Yorùbá àjùmọ̀lò Fún ìdí èyí ni a ṣe yàn láti ṣe àfiwé fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò láàyò nínú iṣẹ́ yìí ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wí pé oríṣìíríṣìí ni àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá nítorí náà iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì láti mọ èdè Ìkálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa èrèdí iṣẹ́ kan ohun tí à ń sọ ni ohun tí ó ṣe okùnfà irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ Iṣẹ́ mọ́lọ́jì ni láti ṣe ìwádìí lórí ètò àti ìlànà tí ìsẹ̀dá ọ̀rọ̀ ń gbà wáyé nígbà tí iṣẹ́ fonọ́lọ́jì jẹ́ ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró nínú èdè kan pàtó Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí ó ṣe okùnfà iṣẹ́ àkànṣe yìí ni láti wo ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè Yorùbá tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó àti láti mọ ètò ìró wọn Síwájú sí i a wòye pé kò tí ì sí iṣẹ́ ìwádìí kan gbòógì tó dá lórí fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ fún ìdí èyí iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò lè fún wa ní òye kíkún lórí ẹ̀kaèdè náà IBI TÍ ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ Kò sí bí ìwádìí ṣe lè gbòòrò tó tí kò ní ní ibi tí yóò mọ Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò sọ fún wa onírúurú ìyànjú tí àwọn onímọ̀ ti ṣe nípa fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá Lára àwọn nǹkan tó jẹ olùwádìí lógún jùlọ ni láti ṣe fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá ohun tí èdè Yorùbá ganan jẹ́ ẹ̀kaèdè àti ètò ìró ní ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí náà ni a ó ti wo ìpilẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí èrèdí iṣẹ́ ìwádìí yìí bákan náà a ó wo àgbéyẹ̀wò aáyan ọ̀mọ̀ràn A ó tún ṣe àfiwé fóníìmù èdè Yorùbá nínú Yorùbá àjùmọ̀lò sí ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ a ó tún wo àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Lákòótán a ó tún wo àmúyẹ iṣẹ́ náà a ó sì dá ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ ọ̀la ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ Oríṣìíríṣìí ọgbọ́n ìwádìí ló wà ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a mú lò nínú wọn Lára àwọn èyí ti a múlò ni wọ̀nyí lílo àtòjọ ìbéèrè ìlànà yìí máa ń ran oníṣẹ́ ìwádìí lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìbéèrè tí yóò bí abẹ́nàìmọ̀ rẹ̀ Lílọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́nàìmọ̀ èyí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ọgbọ́n ìwádìí tí ó wà lílọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́nàìmọ̀ yìí yóò ran olùwádìí lọ́wọ́ àti lè ṣe ìwádìí tómúná dóko lórí iṣẹ́ rẹ̀ Síwájú sí i lílo ìlànà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ibí yìí ni a ti lo ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀ láti fi gba ohùn abẹ́nàìmọ̀ sílẹ̀ láti fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ìbéèrè tí a bi abẹ́nàìmọ̀ Ní àkótán a ṣe àmúlò ìmọ̀ inú ìwé Àwọn ìmọ̀ yìí ni ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyanjú ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Oríṣìíríṣìí ni àǹfààní tí iṣẹ́ ìwádìí yìí lè mú bá ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá àti gírámà èdè Yorùbá àti fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá lápapọ̀ Iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò jẹ́ kí a ní ìmọ̀ tó kún nípa fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò wúlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ iwájú tí wọ́n fẹ́ ṣe ìwádìí lórí àkọlé tí ó farapẹ́ èyí àti láti sọ ìwúlò fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá Ní àkótán tí a bá wo fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá a ó rí i wí pé oríṣìí ìlànà àti ìgbésẹ̀ ni ó ní àwọn ìlànà àti ìgbésẹ̀ bí i àrànmọ́ ìpàrójẹ pẹ̀lú àwọn ìlànà yìí yóò tún ṣe wá ní àǹfààní láti fi lè wo fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ lákọ̀tun ÈTÒ ÌWÁDÌÍ Èròǹgbà iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti ṣe iṣẹ́ lórí fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A pín iṣẹ́ ìwádìí yìí sí orí márùnún tí a sì ṣe ìfáàrà lórí ohun tí ó pilẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí Nínú rẹ̀ ni a ó ti sọ èrèdí iṣẹ́ ìwádìí yìí ibi tí ìwádìí yóò gbòòrò dé ọgbọ́n ìwádìí àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí àti ètò rẹ̀ Nínú orí kejì ni a ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò lórí Aáyan ọ̀mọ̀ràn bákan náà ni a tún ṣe àgbéyẹ̀wò lórí fonọ́lọ́jì àti fònẹ́tíìkì èdè Yorùbá Orí kẹ́ta ni a ó ti sọ̀rọ̀ nípa àfiwé fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ìfáàrà ni ó bẹ̀rẹ̀ orí yìí a ó sì wo àwọn ètò ìró nínú ẹ̀kaèdè náà Ní orí kẹ́rin ni a ti máa wo àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Orí karùnún ni a ti ṣe àgbálọgbábọ̀ ibẹ̀ ni a ó ti wo àmúyẹ lẹ́yìn eléyìí a ó wo ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN ÌFÁÀRÀ Nínú orí yìí ni a ti sọ̀rọ̀ lórí ohun tí èdè jẹ́ ẹ̀kaèdè ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti fònẹ́tíìkì àti fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá Ohun tí ó bá ní ètò tí ó ní ìtumọ̀ tí a sì lè fi ìró gbé jáde ni a mọ̀ sí èdè A sì tún mọ̀ pẹ̀lú pé ara èdè ni a ti rí ẹ̀kaèdè Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró nínú èdè kan pàtó bákan náà nínú fònẹ́tíìkì ni a ti mọ bí a ṣe ń gbé ìró jáde tí ó fi ń di ẹyọ ọ̀rọ̀ Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni a fẹ́ gbé yẹ̀wò nínú orí yìí ÈDÈ YORÙBÁ Èdè jẹ́ ohun ìní ènìyàn nìkan àwùjọ tàbí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ló ní èdè tirẹ̀ Ìdí nìyí tí a fi máa ń sọ pé èdè Yorùbá Haúsá Ìgbò Gẹ̀ẹ́sì Faransé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Oríkì tí a lè fún èdè pọ̀ A lè sọ pé èdè ni ohun tí ó ní ètò àti ìtumọ̀ tí a sì fi ìró èdè gbé jáde Lójú àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè èdè jẹ́ ohun tí ó mú kí àwọn ènìyàn ní àjọsepọ̀ láàárín ara wọn ó sì tún ń mú kí ìròyìn ó máa dé etígbọ̀ọ́ wọn Onímọ̀ kan tí a mọ̀ sí sọ pé Èyí túmọ̀ sí; Èdè kì í ṣe ọ̀nà à ti máa bára ẹni sọ̀rọ̀ fún ìròyìn nípa àkókò tàbí ohun mìíràn bí kò ṣe ọ̀nà láti máa bára ẹni gbépọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn Onímọ̀ mìíràn ni ó ní; Èyí túmọ̀ sí; Èdè ni batani tí a fi ètò ìró ìhun tí ó jẹ́ àtinúdá ènìyàn tí a sọ pọ̀ mọ́ ìṣẹ̀ṣe tí a sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀dá ènìyàn Ọ̀kan nínú àwọn tó ṣe pàtàkì jùlọ láàárín àwọn ọmọ adáríhurun ni èdè ọ̀rọ̀ sísọ àti bíbá ara ẹni sọ̀rọ̀ Èdè ni ohun tí ó ní agbára jùlọ tí a fi máa ń bára ẹni sọ̀rọ̀ ORÍRUN ÈDÈ Ní èrò àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè tàbí onímọ̀ lìngúísíìkì a kò lè ṣo ní pàtó bí èdè ṣe bẹ̀rẹ̀ Kò sí ẹni lè sọ báwo ìgbà wo tàbí ìlànà wo ni èdè gbà bẹ̀rẹ̀ Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípa ìhùwàsí àwọn ẹranko àti ènìyàn kò tí ì rí ojútùú rẹ̀ títí di àsìkò yìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí wọn kò dúró Ó fẹ́rẹ̀ dàbí pé ìmọ̀ nípa ẹ̀sìn àti ìfojúẹ̀sìnwoèdè ni a lè sọ pé ó gbìyànjú díẹ̀ láti gbé èrò nípa orírun èdè yọ Olówóòkéré ṣe àgbékalẹ̀ ohun tí ó kà nípa orirun èdè nínú ìwé Maya tí a ń pè ní pé lẹ́yìn tí Ẹlẹ́dàá dá ohun gbogbo nǹkan tán ló dá àwa ènìyàn láti sọ̀rọ̀ Ó sì fún àwọn ènìyàn ní agbára láti fún èdè yòókù ní orúkọ Wọ́n gbà nínú ìtàn iwase wọ́n pé àwọn ẹranko náà ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi èrò inú wọn hàn ṣùgbọ́n akitiyan láti ní èdè wọn já sí òtubáńtẹ́ Ó ṣe é ṣe kó jẹ́ pé olú ìmísí àbí ìwádìí tí àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè ṣe nìyí tí wọ́n fi sọ pé èdè jẹ́ ohun àdámọ́ ÀBÙDÁ ÈDÈ Àbùdá èdè ni ó máa ń jẹ́ kí a mọ ohun tí èdè jẹ́ ganan oríṣìíríṣìí ni àwọn àbùdá èdè ni Ohun tí a bá pè ní èdè gbọdọ̀ jẹ́ ohun tí a fi ìró èdè gbé jáde Ìró yìí ni a lè pè ní ariwo tí a fi ẹnu pa Èdè nílò kíkọ́ fún ìgbà pípẹ́ díẹ̀ kí ènìyàn tó lè sọ ọ́ Gbogbo èdè kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ìró èdè tirẹ̀ tí à ń pè ní fóníìmù Èdè ọmọ ènìyàn ni ó ṣe é ṣe ohun tí ó bá wà ní ayika wa àti ohun tí ó bá ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ Èdè àwa ẹ̀dá máa ń ní bátànì èyí ni pé ó ní bí àwọn ọ̀rọ̀ ṣe ń papọ̀ pẹ̀lú láti fún wa ní ọ̀rọ̀ Èdè ni a fi fa ẹwà yọ nínú afọ̀ Ẹ̀KAÈDÈ Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wí pé láti ara èdè ni ẹ̀kaẹ̀dá ti jáde ó yẹ kí a mọ ohun tí èdè jẹ kí a tó lè máa sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kaèdè Èdè ni ohun tí ó ní ètò tí ó sì ní ìtumọ̀ tí a sì fi ìró èdè gbé jáde Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni Yorùbá ti ní orúkọ àjùmọ́jẹ́ ti gbogbo ọmọ ilẹ̀ káàárọ̀oòjíire ń pe ara wọn àti èdè wọn ní ayé òde òní Àmọ́ báyìí kọ́ ni nǹkan rí tẹ́lẹ̀ Tẹ́lẹ̀ rí àdúgbò tàbí ẹkùn kọ̀ọ̀kan ni ó ní orúkọ ara rẹ̀ kò sì sí orúkọ kankan gúnmọ́ fún gbogbo wọn àti èdè wọn lápapọ̀ Irú àwọn orúkọ tí ó wà fún ẹkùn kọ̀ọ̀kan nìwọ̀nyí Ìṣẹ́kìrí Ànàgó Ìgalà Akú Ìjẹ̀bú Ọ̀yọ́ Èkìtì Iyàgbà Owé Ẹ̀gbá Ìkálẹ̀ Oǹdó Ifẹ̀ Ọ̀wọ̀ Àkókó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ọ̀nà méjì ni a lè pín àwọn orúkọ tí a kàjọ sókè yìí sí Èkííní jẹ́ ti àwọn tí a o ó pè ní ẹ̀yà èdè Àwọn wọ̀nyí jẹ́ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó bá èdè Yorùbá tan irú àwọn èdè yìí pọ̀ wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò fi lè dárúkọ gbogbo wọn tán Àwọn tí ọ̀nà kejì ni a lè pè ní ẹ̀kaèdè A rí i wí pé àwọn tí ó ń sọ àwọn ẹ̀kaèdè gbogbo wọ́n pọ̀ju àwọn tí ó ń sọ ẹ̀yà ẹ̀kaèdè lọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí àwọn kan nínú wọ́n ṣe máa ń sọ ọ́ lẹ́nu yàtọ̀ sí bí àwọn mìíràn ṣe máa ń sọ ọ́ síbẹ̀ wọn kò ní orúkọ àjùmọ̀jẹ́ kan pàtó fún wọn èdè náà Ó ṣe pàtàkì fún wa láti mọ̀ pé èdè kan kò dára ju ekeji lọ ìbáse èdè Faransé tàbí Fùfúdè Ìgalà tàbí Èbìrà Yorùbá tàbí Ìgbò èdè ni èdè Iṣẹ́ tí èdè kan sì ń ṣe láàárín àwọn tó ń sọ náà ni èdè mìíràn ń ṣe Ó ṣòro láti sọ ní pàtó iye ẹ̀kaèdè tí ó wà nínú èdè Yorùbá ìdí ni pé àwọn ẹ̀yàẹ̀ka pọ̀ nínú àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá Orílẹ̀èdè Nàìjíríà nìkan kọ́ ni a ti ń sọ Yorùbá Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ìkálẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú ọmọ bíbí Odùduwà Odùduwà jẹ́ ọmọ Lámúrúdu Lámúrúdu jẹ́ ọmọ Égíbítì Odùduwà bí ọmọ mẹ́rìndínlógún nínú àwọn ọmọ yìí ọ̀kan nínú wọn ń jẹ́ Monikeneyin Monikeneyin lọ ṣe aṣíwájú ọba Ìkálẹ̀ Ọba Monikeneyin jẹ́ ọdẹ òun ló sì bí Ìkálẹ̀ àti Ìlàjẹ Lẹ́yìn ikú ọba Monikeneyin yìí ni àwọn ọmọ ọba méjèèjì; Ìkálẹ̀ àti Ìlàjẹ wá yapa tí Ìkálẹ̀ dá dúró lọ́tọ̀ tí Ìlàjẹ náà dúró lọ́tọ̀ Níbẹ̀ ni a ti rí Ìkálẹ̀ mẹ́sànán Lára àwọn Ìkálẹ̀ mẹ́sànán náà ni a ti rí; Aye Èrìnjẹ̀ Igbódìgo Ayéka Ìrèlè Àjàgbà àti ÒdeÒmì FÒNẸ́TÍÌKÌ ÀTI FONỌ́LỌ́JÌ Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró inú èdè kan pàtó nínú olórí ẹ̀kaèdè tí a mọ̀ sí Yorùbá àjùmọ̀lò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìró ni a lè pè jáde láti inú ẹnu ìró ni ó ń so pọ̀ di ọ̀rọ̀ tí ọ̀rọ̀ sì di àpólà tí àpólà yìí wá di gbólóhùn fún ìbánisọ̀rọ̀ Adéfilá sọ pé Gbígbé ìró jáde dá lórí ìfọwọ́ṣowọ́pọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí ó jẹ́ kí ìró di gbígbé jáde Táíwò ki fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá báyìí; Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa ìṣàpéjúwe àwọn ìró ìfọ̀ nínú èdè àti bátànì tí àwọn ìróìfọ̀ nínú èdè Fònẹ́tíìkì ń ṣe ìwádìí lórí àbùdá àti ìhun ìró nípa ìlànà mẹ́ta Ọ̀nà kìíní ni àgbéjáde nípasẹ̀ ìṣẹnupè èkéjì ni àbùdá nípasẹ̀ ìfetígbọ́ àti ẹ̀kẹ́ta tí ó jẹ́ àbùdá nípa ìgbọ́àfẹ̀rọwò Àwọn ìlànà tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni àkọ́kọ́ àti ẹ̀kẹ́ta Fònẹ́tíìkì ìṣẹnupè ni ìwádìí bí a ṣe ń gbé ìró jáde láti káà ẹnu Lára àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí à ń lò láti gbé ìró jáde ni ẹ̀dọ̀fóró tánánná àlàfo tánánná gògòńgò imú ètè ẹnu ahọ́n eyín Bákan náà bí àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ wọ̀nyí ṣe ń bá ara wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ láti gbé ìró jáde wà lọ́wọ́ ìró tí a bá pè A ní àfipè àsúnsí àti `afipè àkànmọ́lẹ̀ Lára àwọn àfipè àkànmọ́lẹ̀ ni a ti rí; èrìgì àjàẹnu àfàsé ètè òkè Àpẹẹrẹ àfipè àsúnsí ni a ti rí ètè ìsàlẹ̀ àti ahọ́n Lọ́nà kan sá a lè sọ pé ẹ̀kọ́ nípa onírúurú ìró tí àwọn ènìyàn ń pè jáde nígbà tí a bá ń fọ̀ kí a ṣe àpèjúwe àwọn ìró náà kí a sì pín wọn sí ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí a sì tún ṣàlàyé nípa fáwẹ́lì kọ́ńsónáǹtì àti ohùn inú èdè ni fònẹ́tíìkì jẹ́ nígbà tí ẹ̀kọ́ nípa irú ìró fi ìyàtọ̀ hàn nínú èdè àti ìbátan tí ó wà láàárín àwọn ìró tí ó fi ìyàtọ̀ hàn nínú ọ̀rọ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí kò lè fi ìyàtọ̀ hàn àti bátànì tí à ń lò fún wọn lábẹ́ ohun tí à ń pè ní fonọ́lọ́jì ni a ti ń kọ́ irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ORÍ KẸ́TA FONỌ́LỌ́JÌ ÈDÈ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ SÍ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌFÁÀRÀ Ohun tí a fẹ́ gbéyẹ̀wò nínú orí yìí ni àfiwé fonọ́lọ́jì Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ní orí yìí kan náà ni a ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì àti fáwẹ́lì tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ohun tí ó máa gbẹ̀yìn orí yìí ni àwọn ìró ohùn tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti èyí tí a rí nínú olórí ẹ̀kaèdè Yorùbá FONỌ́LỌ́JÌ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa fonọ́lọ́jì inú èdè kan ohun tí à ń gbìyànjú láti sọ náà ni àbùdá àdáni ìró nínú èdè yẹn pàtó Nínú abala yìí ni a tí máa wo àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì inú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ìró kọ́ńsónáǹtì ni a máa ń pè nígbà tí ìdíwọ́ bá wà fún èémí tí ó ń bọ̀ láti inú ẹ̀dọ̀fóró àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì tí a ní nínú èdè Yorùbá nìwọ̀nyí Bákan náà ìró tí a pè nígbà tí kò sí ìdíwọ́ fún èémí tí ó ń bọ̀ láti inú ẹ̀dọ̀fóró ni ìró fáwẹ́lì Àwọn ìró fáwẹ́lì tí ó wà nínú èdè Yorùbá nìwọ̀myí a e ẹ i o ọ Nínú orí yìí bákan náà ni a ti máa wo ìró ohùn tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ìró ohùn mẹ́ta; ìró ohùn òkè ìró ohùn àárín àti ìró ohùn ìsàlẹ̀ tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni ó wà nínú àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ÌRÓ KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ NÍNÚ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ohun tí a ó yẹ̀wò níbi yìí ni àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì tí a lè rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé nínú àwọn ìró tí a lè bá pàdé nínú Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe pàtàkì kí a ṣe àlàyé tó múná dóko lórí ìró kọ́ńsónáǹtì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A rí àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì wọ̀nyí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ni Àtẹ ìsàlẹ̀ yìí ṣàlàyé ní kíkún lórí kọ́ńsónáǹtì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ÀTẸ KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ọ̀NÀ ÌṢẸNUPÈ Afètèpè Àfeyínfètèpè Afèrìgìpè Afàjàafèrìgìpè Afàjàpè Afafàsépè Afafàsétèpè Àfitánánnápè Tí a bá wo àwọn àpèjúwe yìí àti àpẹẹrẹ kọ̀ọ̀kan lábẹ́ àwọn ìró kọ̀ọ̀kan a rí wí pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ nínú ìró kọ́ńsónáǹtì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò ṣùgbọ́n àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì kan wà tí kò sí nínú Yorùbá àjùmọ̀lò tí ó sì wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró bí i gh gw bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìró kan wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò tí kò sí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ bí i ∫ j y Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀ ní ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì kan wà tí wọ́n fi ń rọ́pọ̀ ara wọn àwọn ìró bí i w fún gh s fún h ÌRÓ FÁWẸ́LÌ NÍNÚ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ohun tí a ó yẹ̀wò níbí yìí ni àwọn ìró fáwẹ́lì tí a lè rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé nínú àwọn ìró tí a lè pàdé nínú Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe pàtàkì kí a ṣe àlàyé tó múná dóko lórí ìró fáwẹ́lì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A rí àwọn ìró fáwẹ́lì wọ̀nyí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ni Àtẹ ìsàlẹ̀ yìí ṣàlàyé kíkún nípa àwọn fáwẹ́lì wọ̀nyí ÀTẸ FÁWẸ́LÌ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ iwájú àárín ẹ̀yìn Ní báyií a ó ṣe àpèjúwe àwọn fáwẹ́lì náà ní ọ̀kọ̀ọ̀kan i àhánupè àìránmúpè iwájú pẹrẹsẹ ÌBẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ ÌRÓ OHÙN ÀÁRÍN NÍNÚ Ẹ̀DÁ ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Bí ìró ohùn àárín ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò náà nì ó lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ à ti pé kò sí ibi tí kò tí lè jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ Bí àpẹẹrẹ ÌRÓ OHÙN ÌSÀLẸ̀ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Bí ìró ohùn ìsàlẹ̀ ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ní Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà nì ó ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ Ìró ohùn ìsàlẹ̀ sì lè jeyọ ni ìpòkípò nínú ọ̀rọ̀ ìyẹn ní ìbẹ̀rẹ̀ àárín àti ìparí ọ̀rọ̀ Bí àpẹẹrẹ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÌJẸYỌPỌ̀ OHÙN NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Oríṣìí ẹ̀yà ohùn mẹ́tẹ̀ta ni wọ́n ní àǹfààní láti jẹyọ pẹ̀lú ara wọn kó dà nínú ọ̀rọ̀ onísílébù mèjì OHÙN ÌSÀLẸ̀ OHÙN ÒKÈ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ yẹ̀nyẹ́n yìnyín ìgbín ẹ̀gbọ́n ìgbẹ́ OHÙN ÀÁRÍN OHÙN ÒKÈ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ilé iṣẹ́ inú imú OHÙN ÀÁRÍN OHÙN ÀÁRÍN ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ irin orin epo epo OHÙN ÌSÀLẸ̀ OHÙN ÀÁRÍN ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ẹsẹ̀ nǹkan ìwo òni OHÙN ÌSÀLẸ̀ OHÙN ÌSÀLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ òsì ata ọ̀fọ̀ ọ̀rọ̀ hùn sìn mà mọ̀ Ohùn métẹ̀ta náà lè jẹjọ papọ̀ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń jeyọ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò OHÙN ÒKÈ OHÙN ÀÁRÍN OHÙN ÌSÀLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ mọwọ́kàn fowọ̀kàn yírapadà yípadà múpadà dápadà fàhọ́nmára fàmọ́ra ORÍ KẸ́RIN ÀWỌN ÌGBÉSẸ̀ FONỌ́LỌ́JÌ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌFÁÀRÀ Nínú orí yìí ni a ti máa wo àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tí ó jẹyọ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì bí i àrànmọ́ àti oríṣìí àrànmọ́ tí ó wà ìpàrójẹ́ ìpajẹ fáwẹ́lì àti ìpajẹ kọ́ńṣónáǹtì àǹkóò fáwẹ́lì ÀRÀNMỌ́ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Nínú abala yìí ohùn tí fẹ́ gbé yẹ̀wò náà ni àrànmọ́ tó súyọ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn oríṣìí àrànmọ́ tí a fẹ́ gbé yẹ̀wò náà ni àrànmọ́ iwájú àrànmọ́ ẹ̀yìn àrànmọ́ aláìfòró àrànmọ́ afòró ṣùgbọ́n ki a tó tẹ̀síwájú ó yẹ ki a mọ ohùn tí àrànmọ́ jẹ́ Gẹ́gẹ́ bí Oyèbádé ti ki àrànmọ́ ó ní; Ohùn tì onímọ̀ yìí ń gbìyànjú láti sọ náà ni wí pé nígbà tí ìró méjì tí ó jẹ́ nǹkankan náà tàbí tí ó yàtọ̀ si ara wọn bá dí ìró kan pé àrànmọ́ ti wáyé nìyẹn Ó tún wà tẹ̀síwájú nínú àlàyé tí o ń ṣe lórí àrànmọ́ ó ní Ohùn tí onímọ̀ yìí ń gbìyànjú láti sọ láti òkè náà ni pé ìró afàrànmọ̀ wà ìró agbàrànmọ̀ sì wà pẹ̀lú A lè wo bí àrànmọ́ ṣe rìn láti sọ irú àrànmọ́ tó wáyé ÀRÀNMỌ́WÁJÚ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÀRÀNMỌ́ ALÁÌFÒRÓ NÍNÚ Ẹ̀KA ÌKÁLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÀRÀNMỌ́ AFÒRÓ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÌPAJẸ KỌ́ŃṢÓNÁǸTÌ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ ìpajẹ kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n wón sábà máa ń pa kọ́ńṣónáǹtì r àti n jẹ́ r ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÌPAJẸ FÁWẸ́LÌ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìpajẹ fáwẹ́lì nínú èdè kan èyí máa ń wáyé nígbà tí fáwẹ́lì méjì bá fì ẹgbẹ̀kẹ̀gbẹ̀ ni àlàfo ọ̀rọ̀ Èyí túmọ̀ sí pé fáwẹ́lì lo gbọdọ̀ parí ọ̀rọ̀ àkókò tí fáwẹ́lì sì gbọdọ̀ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ kejì Nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ fáwẹ́lì ọ̀rọ̀iṣẹ́ ti ó jẹ́ àìránmípè nìkan ni a sábà máa ń pajẹ tí a sì máa ń dá ti ọ̀rọ̀ orúkọ sí ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ lukọ ÀNKÓÒ FÁWẸ́LÌ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ fáwẹ́lì àìránmúpè méje ni wọ́n ni tí fáwẹ́lì u sì lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn A lè pín ànkóò fáwẹ́lì ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ si ọ̀wọ́ méjì báyìí Ọ́wọ́ Òwọ́ Àpẹẹrẹ ànkóò fáwẹ́lì ọ̀wọ́ nínú ìkaèdè Ìkálẹ̀ Ọ̀WỌ́ Àpẹẹrẹ ànkóò fáwẹ́lì ọ̀wọ́ nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ Ọ̀WỌ́ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ Nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ẹ̀wẹ̀ àwọn fáwẹ́lì ọ̀rọ̀ méjéèjì lè bá ara wọn siṣẹ́ nínú ọ̀rọ̀ Òwọ̀ àti ọ̀wọ́ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÌGÚNLẸ̀ Tí a bà wo ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ìyàtọ̀ díẹ̀ náà ló wà nínú bí a ṣe ń pé àwọn ọ̀rọ̀ kan Ohùn tí ó tún fẹ́ jẹ́ ìyàtọ̀ ni pé àwọn kọ́ńsónáǹtì kan wà ti kò sí nínú Yorùbá àjùmọ̀lò ti ó sì wà ni ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn kọ́ńṣónáǹtì bí i gh àti gw Bàkan náà kò sì kọ́ńṣónáǹtì ∫ nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ tí ó sì wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò Ìró fáwẹ́lì tí ó sì wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni ó wà ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ohùn mìíràn tí ó jẹ ìyàtọ̀ tó fẹ́ wà láàárín ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni wí pé ní ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ wọ́n máa ń fi fáwẹ́lì u bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn bí àpẹẹrẹ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ Bákan náà wọ́n tún máa ń lo kọ́ńṣónáǹtì h fún s bí àpẹẹrẹ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ ÌFÁÀRÀ Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wi pé orí ti ó gbẹ̀yìn iṣẹ́ ìwádìí yìí ni a dé yìí Nínú orí yìí ni a ó ti ṣe àgbálọgbábọ̀ gbogbo ohun tí a ń sọ bọ̀ lórí iṣẹ́ àkànṣe yìí Nínú orí yìí ni a ó ṣe ìsọnísókí àbajáde ìwádìí àmúyẹ àti ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ÌSONÍSÓKÍ ÀBỌ̀ ÌWÁDÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wi pé ohun tí iṣẹ́ àkànṣe yìí dálé ni fonọ́lọ́jì ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ tí a si ṣe àfiwé rẹ̀ pẹ̀lú Yorùbá àjùmọ̀lò nínú orí mẹrin tí iṣẹ́ yìí pin si Láti Ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ni ó ti farahàn pé ipò pàtàkì ni fonọ́lọ́jì wà láàárín gírámà èdè ní àgbáyé tí kò si yọ èdè Yorùbá sílẹ̀ náà ni a ṣe ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí fonọ́lọ́jì jẹ́ Gẹ́gẹ́ bí a ti kí fonọ́lọ́jì aní fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa ìsàpèjúwa àwọn ìróifọ̀ nínú èdè àti bátànì tí àwọn ìróifọ̀ ní nínú èdè bàkan náà a tun ki fònẹ́tíìkì torí pé àti fonọ́lọ́jì àti fònẹ́tíìkì àwọn méjèèjì ń bá ara wọ́n ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ gírámà A wo ohun ti èdè jẹ́ orírun èdè àbùdá èdè A si tun wo ohun ti ẹ̀ka èdè jẹ́ fún ra rẹ̀ àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ nítorí pé fonọ́lọ́jì ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ ni a ṣe Bákan náà a wo àwọn ìró tí a lè bà pàdé nínú ẹ̀dáèdè Ìkálẹ̀ èyí ni àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì ìró fáwẹ́lì àti ìró ohùn A yẹ àwọn ìgbèsẹ̀ fonọ́lọ́jì ti a lè rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì bí i àrànmọ́ ìpàrójẹ́ ti a si wo ìyàtọ̀ tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ tí a si ṣe ìgínlẹ̀ lórí gbogbo rẹ̀ ÀMÚYẸ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé kò sí bí iṣẹ́ kan ṣe lè wà tí kò ní ní àwọn àmúyẹ kan tàbí òmíràn Lára àwọn àmúyẹ inú iṣẹ́ yìí ni pé ó mú kí a ní ìmọ̀ tó dájú nípa ìlú Ìkálẹ̀ ti ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ìpínlẹ̀ Òndó ó tun jẹ́ ki a mọ bí àwọn Ìkálẹ̀ ṣe ń pé ìró àti bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn ìró jáde Ohùn mìíràn tí ó tun ṣe pàtàkì ni pé ó jẹ́ ki a mọ àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà nínú àwọn ìró kan nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò o sí tun jẹ́ kí a mọ iye ìró kọ́ńṣónáǹtì àti ìró fáwẹ́lì tí ó wà nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ ó jẹ́ ki a mọ̀ wí pé ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ wà lára àwọn ẹ̀kaèdè tí wọ́n ní fáwẹ́lì àìránmúpè méje tí fáwẹ́lì u si lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn Lákòtán ó jẹ́ ki á mọ̀ ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè Yorùbá tí ó ṣe pàtàkì tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè tí ó gbájugbajà láàárín ilẹ̀ Yorùbá ÌMỌ̀RÀN FÚN ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé iṣẹ́ àkànṣe yìí dálé fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ìmọ̀ràn mi fún oníṣẹ́ ìwádìí ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ìpele gírámà tí ó wà àwọn ìpele gírámà bí i mọfọ́lọ́jì síntáàsì oníṣẹ́ ìwádìí le ṣiṣẹ́ lórí àwọn wọ̀nyí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ tàbí nínú ẹ̀kaèdè mìíràn ÌKÁDÌÍ A ti gbìyànjú láti ṣe àgbéyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ nígbà tí a ti mọ ohun tí fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá jẹ́ èdè Yorùbá àti ẹ̀kaèdè tí a sì ti yẹ àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ wò Bákan náà a rí i wí pé ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè Yorùbá tí a kò lè fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ni ẹ̀kaèdè yìí jẹ́ nínú èdè Yorùbá ÀKÓJỌ ORÚKỌ ÌWÉ Àjàyí Ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá Ẹ̀dáÈdè Lítíréṣọ̀ àti Àṣà IjebuOde Sebiotimọ Awóbùlúyì Yorùbá Metalanguage II Èdè Ìperí Yorùbá Ìbàdàn Bámgbóṣé A Yorùbá Metalanguage I Èdè Ìperí Yorùbá Bámgbóṣé A Fonọ́lọ́jì àti Gírámà Yorùbá Ìbàdàn Odùyẹmí SO Àfiwé Fonọ́lọ́jì Ẹ̀kaÈdè Akúrẹ́ àti Yorùbá Àjùmọ̀lò Iṣẹ́ Àṣekágbá Fún Gbígba Oyè Bíi Eè Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè àti Èdè Ilẹ̀ Nàìjíríà Ìlọrin Olúnládé T Èdè Yorùbá àti Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè Fọlá Oyèbádé Oyè T Mọ́lọ́jì ORÍ KÌÍNÍ ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌFÁÀRÀ Yorùbá gẹ́gẹ́ bí èdè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tí ó sì gbajúgbajà káàkiri àgbáyé Fún ìdí èyí kò ní sàìjẹ́ èdè tí à ń ṣiṣẹ́ lé lórí nítorí ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ Kí ó tó di wí pé èdè Yorùbá dé ibi tí ó dé lónìí àwọn onímọ̀ bí i ti ó ṣe iṣẹ́ àkọ́kọ́ lórí àyẹ̀wò àwọn ẹ̀kaèdè ni ó ti ṣe iṣẹ́ takuntakun lórí rẹ̀ Ní báyìí kò jẹ́ ìyálẹ́nu láti sọ wí pé èdè tí a mọ̀ sí Yorùbá jẹ́ eléyìí tí a lè pín sí ẹ̀ka méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ báyìí Yorùbá àjùmọ̀lò àti àwọn ẹ̀kaèdè abẹ́ rẹ̀ Nígbà tí ó ti wá rí báyìí yóò jẹ́ ohun tí ó dára àti ohun àmúyangàn láti mọ ìyàtọ̀ tàbí ìjọra tó wà láàárín ẹ̀kaèdè kan pàtó àti Yorùbá àjùmọ̀lò Fún ìdí èyí ni a ṣe yàn láti ṣe àfiwé fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò láàyò nínú iṣẹ́ yìí ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wí pé oríṣìíríṣìí ni àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá nítorí náà iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì láti mọ èdè Ìkálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa èrèdí iṣẹ́ kan ohun tí à ń sọ ni ohun tí ó ṣe okùnfà irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ Iṣẹ́ mọ́lọ́jì ni láti ṣe ìwádìí lórí ètò àti ìlànà tí ìsẹ̀dá ọ̀rọ̀ ń gbà wáyé nígbà tí iṣẹ́ fonọ́lọ́jì jẹ́ ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró nínú èdè kan pàtó Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí ó ṣe okùnfà iṣẹ́ àkànṣe yìí ni láti wo ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè Yorùbá tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó àti láti mọ ètò ìró wọn Síwájú sí i a wòye pé kò tí ì sí iṣẹ́ ìwádìí kan gbòógì tó dá lórí fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ fún ìdí èyí iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò lè fún wa ní òye kíkún lórí ẹ̀kaèdè náà IBI TÍ ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ Kò sí bí ìwádìí ṣe lè gbòòrò tó tí kò ní ní ibi tí yóò mọ Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò sọ fún wa onírúurú ìyànjú tí àwọn onímọ̀ ti ṣe nípa fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá Lára àwọn nǹkan tó jẹ olùwádìí lógún jùlọ ni láti ṣe fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá ohun tí èdè Yorùbá ganan jẹ́ ẹ̀kaèdè àti ètò ìró ní ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí náà ni a ó ti wo ìpilẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí èrèdí iṣẹ́ ìwádìí yìí bákan náà a ó wo àgbéyẹ̀wò aáyan ọ̀mọ̀ràn A ó tún ṣe àfiwé fóníìmù èdè Yorùbá nínú Yorùbá àjùmọ̀lò sí ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ a ó tún wo àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Lákòótán a ó tún wo àmúyẹ iṣẹ́ náà a ó sì dá ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ ọ̀la ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ Oríṣìíríṣìí ọgbọ́n ìwádìí ló wà ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a mú lò nínú wọn Lára àwọn èyí ti a múlò ni wọ̀nyí lílo àtòjọ ìbéèrè ìlànà yìí máa ń ran oníṣẹ́ ìwádìí lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìbéèrè tí yóò bí abẹ́nàìmọ̀ rẹ̀ Lílọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́nàìmọ̀ èyí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ọgbọ́n ìwádìí tí ó wà lílọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́nàìmọ̀ yìí yóò ran olùwádìí lọ́wọ́ àti lè ṣe ìwádìí tómúná dóko lórí iṣẹ́ rẹ̀ Síwájú sí i lílo ìlànà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ibí yìí ni a ti lo ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀ láti fi gba ohùn abẹ́nàìmọ̀ sílẹ̀ láti fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ìbéèrè tí a bi abẹ́nàìmọ̀ Ní àkótán a ṣe àmúlò ìmọ̀ inú ìwé Àwọn ìmọ̀ yìí ni ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyanjú ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Oríṣìíríṣìí ni àǹfààní tí iṣẹ́ ìwádìí yìí lè mú bá ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá àti gírámà èdè Yorùbá àti fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá lápapọ̀ Iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò jẹ́ kí a ní ìmọ̀ tó kún nípa fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò wúlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ iwájú tí wọ́n fẹ́ ṣe ìwádìí lórí àkọlé tí ó farapẹ́ èyí àti láti sọ ìwúlò fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá Ní àkótán tí a bá wo fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá a ó rí i wí pé oríṣìí ìlànà àti ìgbésẹ̀ ni ó ní àwọn ìlànà àti ìgbésẹ̀ bí i àrànmọ́ ìpàrójẹ pẹ̀lú àwọn ìlànà yìí yóò tún ṣe wá ní àǹfààní láti fi lè wo fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ lákọ̀tun ÈTÒ ÌWÁDÌÍ Èròǹgbà iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti ṣe iṣẹ́ lórí fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A pín iṣẹ́ ìwádìí yìí sí orí márùnún tí a sì ṣe ìfáàrà lórí ohun tí ó pilẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí Nínú rẹ̀ ni a ó ti sọ èrèdí iṣẹ́ ìwádìí yìí ibi tí ìwádìí yóò gbòòrò dé ọgbọ́n ìwádìí àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí àti ètò rẹ̀ Nínú orí kejì ni a ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò lórí Aáyan ọ̀mọ̀ràn bákan náà ni a tún ṣe àgbéyẹ̀wò lórí fonọ́lọ́jì àti fònẹ́tíìkì èdè Yorùbá Orí kẹ́ta ni a ó ti sọ̀rọ̀ nípa àfiwé fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ìfáàrà ni ó bẹ̀rẹ̀ orí yìí a ó sì wo àwọn ètò ìró nínú ẹ̀kaèdè náà Ní orí kẹ́rin ni a ti máa wo àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Orí karùnún ni a ti ṣe àgbálọgbábọ̀ ibẹ̀ ni a ó ti wo àmúyẹ lẹ́yìn eléyìí a ó wo ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN ÌFÁÀRÀ Nínú orí yìí ni a ti sọ̀rọ̀ lórí ohun tí èdè jẹ́ ẹ̀kaèdè ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti fònẹ́tíìkì àti fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá Ohun tí ó bá ní ètò tí ó ní ìtumọ̀ tí a sì lè fi ìró gbé jáde ni a mọ̀ sí èdè A sì tún mọ̀ pẹ̀lú pé ara èdè ni a ti rí ẹ̀kaèdè Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró nínú èdè kan pàtó bákan náà nínú fònẹ́tíìkì ni a ti mọ bí a ṣe ń gbé ìró jáde tí ó fi ń di ẹyọ ọ̀rọ̀ Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni a fẹ́ gbé yẹ̀wò nínú orí yìí ÈDÈ YORÙBÁ Èdè jẹ́ ohun ìní ènìyàn nìkan àwùjọ tàbí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ló ní èdè tirẹ̀ Ìdí nìyí tí a fi máa ń sọ pé èdè Yorùbá Haúsá Ìgbò Gẹ̀ẹ́sì Faransé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Oríkì tí a lè fún èdè pọ̀ A lè sọ pé èdè ni ohun tí ó ní ètò àti ìtumọ̀ tí a sì fi ìró èdè gbé jáde Lójú àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè èdè jẹ́ ohun tí ó mú kí àwọn ènìyàn ní àjọsepọ̀ láàárín ara wọn ó sì tún ń mú kí ìròyìn ó máa dé etígbọ̀ọ́ wọn Onímọ̀ kan tí a mọ̀ sí sọ pé Èyí túmọ̀ sí; Èdè kì í ṣe ọ̀nà à ti máa bára ẹni sọ̀rọ̀ fún ìròyìn nípa àkókò tàbí ohun mìíràn bí kò ṣe ọ̀nà láti máa bára ẹni gbépọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn Onímọ̀ mìíràn ni ó ní; Èyí túmọ̀ sí; Èdè ni batani tí a fi ètò ìró ìhun tí ó jẹ́ àtinúdá ènìyàn tí a sọ pọ̀ mọ́ ìṣẹ̀ṣe tí a sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀dá ènìyàn Ọ̀kan nínú àwọn tó ṣe pàtàkì jùlọ láàárín àwọn ọmọ adáríhurun ni èdè ọ̀rọ̀ sísọ àti bíbá ara ẹni sọ̀rọ̀ Èdè ni ohun tí ó ní agbára jùlọ tí a fi máa ń bára ẹni sọ̀rọ̀ ORÍRUN ÈDÈ Ní èrò àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè tàbí onímọ̀ lìngúísíìkì a kò lè ṣo ní pàtó bí èdè ṣe bẹ̀rẹ̀ Kò sí ẹni lè sọ báwo ìgbà wo tàbí ìlànà wo ni èdè gbà bẹ̀rẹ̀ Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípa ìhùwàsí àwọn ẹranko àti ènìyàn kò tí ì rí ojútùú rẹ̀ títí di àsìkò yìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí wọn kò dúró Ó fẹ́rẹ̀ dàbí pé ìmọ̀ nípa ẹ̀sìn àti ìfojúẹ̀sìnwoèdè ni a lè sọ pé ó gbìyànjú díẹ̀ láti gbé èrò nípa orírun èdè yọ Olówóòkéré ṣe àgbékalẹ̀ ohun tí ó kà nípa orirun èdè nínú ìwé Maya tí a ń pè ní pé lẹ́yìn tí Ẹlẹ́dàá dá ohun gbogbo nǹkan tán ló dá àwa ènìyàn láti sọ̀rọ̀ Ó sì fún àwọn ènìyàn ní agbára láti fún èdè yòókù ní orúkọ Wọ́n gbà nínú ìtàn iwase wọ́n pé àwọn ẹranko náà ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi èrò inú wọn hàn ṣùgbọ́n akitiyan láti ní èdè wọn já sí òtubáńtẹ́ Ó ṣe é ṣe kó jẹ́ pé olú ìmísí àbí ìwádìí tí àwọn onímọ̀ ẹ̀dáèdè ṣe nìyí tí wọ́n fi sọ pé èdè jẹ́ ohun àdámọ́ ÀBÙDÁ ÈDÈ Àbùdá èdè ni ó máa ń jẹ́ kí a mọ ohun tí èdè jẹ́ ganan oríṣìíríṣìí ni àwọn àbùdá èdè ni Ohun tí a bá pè ní èdè gbọdọ̀ jẹ́ ohun tí a fi ìró èdè gbé jáde Ìró yìí ni a lè pè ní ariwo tí a fi ẹnu pa Èdè nílò kíkọ́ fún ìgbà pípẹ́ díẹ̀ kí ènìyàn tó lè sọ ọ́ Gbogbo èdè kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ìró èdè tirẹ̀ tí à ń pè ní fóníìmù Èdè ọmọ ènìyàn ni ó ṣe é ṣe ohun tí ó bá wà ní ayika wa àti ohun tí ó bá ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ Èdè àwa ẹ̀dá máa ń ní bátànì èyí ni pé ó ní bí àwọn ọ̀rọ̀ ṣe ń papọ̀ pẹ̀lú láti fún wa ní ọ̀rọ̀ Èdè ni a fi fa ẹwà yọ nínú afọ̀ Ẹ̀KAÈDÈ Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wí pé láti ara èdè ni ẹ̀kaẹ̀dá ti jáde ó yẹ kí a mọ ohun tí èdè jẹ kí a tó lè máa sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kaèdè Èdè ni ohun tí ó ní ètò tí ó sì ní ìtumọ̀ tí a sì fi ìró èdè gbé jáde Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni Yorùbá ti ní orúkọ àjùmọ́jẹ́ ti gbogbo ọmọ ilẹ̀ káàárọ̀oòjíire ń pe ara wọn àti èdè wọn ní ayé òde òní Àmọ́ báyìí kọ́ ni nǹkan rí tẹ́lẹ̀ Tẹ́lẹ̀ rí àdúgbò tàbí ẹkùn kọ̀ọ̀kan ni ó ní orúkọ ara rẹ̀ kò sì sí orúkọ kankan gúnmọ́ fún gbogbo wọn àti èdè wọn lápapọ̀ Irú àwọn orúkọ tí ó wà fún ẹkùn kọ̀ọ̀kan nìwọ̀nyí Ìṣẹ́kìrí Ànàgó Ìgalà Akú Ìjẹ̀bú Ọ̀yọ́ Èkìtì Iyàgbà Owé Ẹ̀gbá Ìkálẹ̀ Oǹdó Ifẹ̀ Ọ̀wọ̀ Àkókó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ọ̀nà méjì ni a lè pín àwọn orúkọ tí a kàjọ sókè yìí sí Èkííní jẹ́ ti àwọn tí a o ó pè ní ẹ̀yà èdè Àwọn wọ̀nyí jẹ́ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó bá èdè Yorùbá tan irú àwọn èdè yìí pọ̀ wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò fi lè dárúkọ gbogbo wọn tán Àwọn tí ọ̀nà kejì ni a lè pè ní ẹ̀kaèdè A rí i wí pé àwọn tí ó ń sọ àwọn ẹ̀kaèdè gbogbo wọ́n pọ̀ju àwọn tí ó ń sọ ẹ̀yà ẹ̀kaèdè lọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí àwọn kan nínú wọ́n ṣe máa ń sọ ọ́ lẹ́nu yàtọ̀ sí bí àwọn mìíràn ṣe máa ń sọ ọ́ síbẹ̀ wọn kò ní orúkọ àjùmọ̀jẹ́ kan pàtó fún wọn èdè náà Ó ṣe pàtàkì fún wa láti mọ̀ pé èdè kan kò dára ju ekeji lọ ìbáse èdè Faransé tàbí Fùfúdè Ìgalà tàbí Èbìrà Yorùbá tàbí Ìgbò èdè ni èdè Iṣẹ́ tí èdè kan sì ń ṣe láàárín àwọn tó ń sọ náà ni èdè mìíràn ń ṣe Ó ṣòro láti sọ ní pàtó iye ẹ̀kaèdè tí ó wà nínú èdè Yorùbá ìdí ni pé àwọn ẹ̀yàẹ̀ka pọ̀ nínú àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá Orílẹ̀èdè Nàìjíríà nìkan kọ́ ni a ti ń sọ Yorùbá Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ìkálẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú ọmọ bíbí Odùduwà Odùduwà jẹ́ ọmọ Lámúrúdu Lámúrúdu jẹ́ ọmọ Égíbítì Odùduwà bí ọmọ mẹ́rìndínlógún nínú àwọn ọmọ yìí ọ̀kan nínú wọn ń jẹ́ Monikeneyin Monikeneyin lọ ṣe aṣíwájú ọba Ìkálẹ̀ Ọba Monikeneyin jẹ́ ọdẹ òun ló sì bí Ìkálẹ̀ àti Ìlàjẹ Lẹ́yìn ikú ọba Monikeneyin yìí ni àwọn ọmọ ọba méjèèjì; Ìkálẹ̀ àti Ìlàjẹ wá yapa tí Ìkálẹ̀ dá dúró lọ́tọ̀ tí Ìlàjẹ náà dúró lọ́tọ̀ Níbẹ̀ ni a ti rí Ìkálẹ̀ mẹ́sànán Lára àwọn Ìkálẹ̀ mẹ́sànán náà ni a ti rí; Aye Èrìnjẹ̀ Ùgbódìgo Ayéka Ìrèlè Àjàgbà àti ÒdeÒmì FÒNẸ́TÍÌKÌ ÀTI FONỌ́LỌ́JÌ Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ tí a ti máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àbùdá àdáni ìró inú èdè kan pàtó nínú olórí ẹ̀kaèdè tí a mọ̀ sí Yorùbá àjùmọ̀lò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìró ni a lè pè jáde láti inú ẹnu ìró ni ó ń so pọ̀ di ọ̀rọ̀ tí ọ̀rọ̀ sì di àpólà tí àpólà yìí wá di gbólóhùn fún ìbánisọ̀rọ̀ Adéfilá sọ pé Gbígbé ìró jáde dá lórí ìfọwọ́ṣowọ́pọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí ó jẹ́ kí ìró di gbígbé jáde Táíwò ki fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá báyìí; Fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa ìṣàpéjúwe àwọn ìró ìfọ̀ nínú èdè àti bátànì tí àwọn ìróìfọ̀ nínú èdè Fònẹ́tíìkì ń ṣe ìwádìí lórí àbùdá àti ìhun ìró nípa ìlànà mẹ́ta Ọ̀nà kìíní ni àgbéjáde nípasẹ̀ ìṣẹnupè èkéjì ni àbùdá nípasẹ̀ ìfetígbọ́ àti ẹ̀kẹ́ta tí ó jẹ́ àbùdá nípa ìgbọ́àfẹ̀rọwò Àwọn ìlànà tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni àkọ́kọ́ àti ẹ̀kẹ́ta Fònẹ́tíìkì ìṣẹnupè ni ìwádìí bí a ṣe ń gbé ìró jáde láti káà ẹnu Lára àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí à ń lò láti gbé ìró jáde ni ẹ̀dọ̀fóró tánánná àlàfo tánánná gògòńgò imú ètè ẹnu ahọ́n eyín Bákan náà bí àwọn ẹ̀yà ara ìfọ̀ wọ̀nyí ṣe ń bá ara wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ láti gbé ìró jáde wà lọ́wọ́ ìró tí a bá pè A ní àfipè àsúnsí àti `afipè àkànmọ́lẹ̀ Lára àwọn àfipè àkànmọ́lẹ̀ ni a ti rí; èrìgì àjàẹnu àfàsé ètè òkè Àpẹẹrẹ àfipè àsúnsí ni a ti rí ètè ìsàlẹ̀ àti ahọ́n Lọ́nà kan sá a lè sọ pé ẹ̀kọ́ nípa onírúurú ìró tí àwọn ènìyàn ń pè jáde nígbà tí a bá ń fọ̀ kí a ṣe àpèjúwe àwọn ìró náà kí a sì pín wọn sí ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí a sì tún ṣàlàyé nípa fáwẹ́lì kọ́ńsónáǹtì àti ohùn inú èdè ni fònẹ́tíìkì jẹ́ nígbà tí ẹ̀kọ́ nípa irú ìró fi ìyàtọ̀ hàn nínú èdè àti ìbátan tí ó wà láàárín àwọn ìró tí ó fi ìyàtọ̀ hàn nínú ọ̀rọ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí kò lè fi ìyàtọ̀ hàn àti bátànì tí à ń lò fún wọn lábẹ́ ohun tí à ń pè ní fonọ́lọ́jì ni a ti ń kọ́ irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ORÍ KẸ́TA FONỌ́LỌ́JÌ ÈDÈ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ SÍ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌFÁÀRÀ Ohun tí a fẹ́ gbéyẹ̀wò nínú orí yìí ni àfiwé fonọ́lọ́jì Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ní orí yìí kan náà ni a ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì àti fáwẹ́lì tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ohun tí ó máa gbẹ̀yìn orí yìí ni àwọn ìró ohùn tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti èyí tí a rí nínú olórí ẹ̀kaèdè Yorùbá FONỌ́LỌ́JÌ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa fonọ́lọ́jì inú èdè kan ohun tí à ń gbìyànjú láti sọ náà ni àbùdá àdáni ìró nínú èdè yẹn pàtó Nínú abala yìí ni a tí máa wo àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì inú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ìró kọ́ńsónáǹtì ni a máa ń pè nígbà tí ìdíwọ́ bá wà fún èémí tí ó ń bọ̀ láti inú ẹ̀dọ̀fóró àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì tí a ní nínú èdè Yorùbá nìwọ̀nyí Bákan náà ìró tí a pè nígbà tí kò sí ìdíwọ́ fún èémí tí ó ń bọ̀ láti inú ẹ̀dọ̀fóró ni ìró fáwẹ́lì Àwọn ìró fáwẹ́lì tí ó wà nínú èdè Yorùbá nìwọ̀myí a e ẹ i o ọ Nínú orí yìí bákan náà ni a ti máa wo ìró ohùn tí ó wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ìró ohùn mẹ́ta; ìró ohùn òkè ìró ohùn àárín àti ìró ohùn ìsàlẹ̀ tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni ó wà nínú àwọn ẹ̀kaèdè Yorùbá àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ÌRÓ KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ NÍNÚ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ohun tí a ó yẹ̀wò níbi yìí ni àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì tí a lè rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé nínú àwọn ìró tí a lè bá pàdé nínú Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe pàtàkì kí a ṣe àlàyé tó múná dóko lórí ìró kọ́ńsónáǹtì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A rí àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì wọ̀nyí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ni Àtẹ ìsàlẹ̀ yìí ṣàlàyé ní kíkún lórí kọ́ńsónáǹtì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ÀTẸ KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ọ̀NÀ ÌṢẸNUPÈ Afètèpè Àfeyínfètèpè Afèrìgìpè Afàjàafèrìgìpè Afàjàpè Afafàsépè Afafàsétèpè Àfitánánnápè Tí a bá wo àwọn àpèjúwe yìí àti àpẹẹrẹ kọ̀ọ̀kan lábẹ́ àwọn ìró kọ̀ọ̀kan a rí wí pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ nínú ìró kọ́ńsónáǹtì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò ṣùgbọ́n àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì kan wà tí kò sí nínú Yorùbá àjùmọ̀lò tí ó sì wà nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró bí i gh gw bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìró kan wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò tí kò sí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ bí i ∫ j y Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀ ní ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì kan wà tí wọ́n fi ń rọ́pọ̀ ara wọn àwọn ìró bí i w fún gh s fún h ÌRÓ FÁWẸ́LÌ NÍNÚ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ohun tí a ó yẹ̀wò níbí yìí ni àwọn ìró fáwẹ́lì tí a lè rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé nínú àwọn ìró tí a lè pàdé nínú Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe pàtàkì kí a ṣe àlàyé tó múná dóko lórí ìró fáwẹ́lì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ A rí àwọn ìró fáwẹ́lì wọ̀nyí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn ni Àtẹ ìsàlẹ̀ yìí ṣàlàyé kíkún nípa àwọn fáwẹ́lì wọ̀nyí ÀTẸ FÁWẸ́LÌ Ẹ̀KAÈDÈ ÌKÁLẸ̀ kó fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ nínú àwọn ìró fáwẹ́lì tí ó wà ni Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè ìkálẹ̀ pípè àti gbígbé àwọn ìró náà jade nìkan nì ó fi ìyàtọ̀ hàn Nínú ẹ̀kaèdè ìkálẹ̀ wọ́n sábà máa ń fi àwọn ìró kan rọpò ara wọn nígbà mìíràn bí àpẹẹrẹ ìró bí i i fún a bí àpẹẹrẹ ÌRÓ OHÙN NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Oríṣìí ìró ohùn mẹ́ta tí ó wà ní Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni ó wà nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ àwọn ìró ohùn wọ̀nyí Ìró ohùn òkè i Ìró ohùn àárín Ìró ohùn ìsàlẹ̀ ÌRÓ OHÙN OKE NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Bí ìró ohùn òkè kò tìlè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀ yìí fihàn pé ìró ohùn òkè kò lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ni ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÌRÓ OHÙN ÀÁRÍN NÍNÚ Ẹ̀DÁ ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Bí ìró ohùn àárín ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò náà nì ó lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ à ti pé kò sí ibi tí kò tí lè jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ Bí àpẹẹrẹ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÌRÓ OHÙN ÌSÀLẸ̀ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Bí ìró ohùn ìsàlẹ̀ ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ní Yorùbá àjùmọ̀lò bẹ́ẹ̀ náà nì ó ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ Ìró ohùn ìsàlẹ̀ sì lè jeyọ ni ìpòkípò nínú ọ̀rọ̀ ìyẹn ní ìbẹ̀rẹ̀ àárín àti ìparí ọ̀rọ̀ Bí àpẹẹrẹ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ìbàtíyẹn ọ̀gẹ̀dẹ̀ dòdò ÌJẸYỌPỌ̀ OHÙN NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Oríṣìí ẹ̀yà ohùn mẹ́tẹ̀ta ni wọ́n ní àǹfààní láti jẹyọ pẹ̀lú ara wọn kó dà nínú ọ̀rọ̀ onísílébù mèjì OHÙN ÌSÀLẸ̀ OHÙN ÒKÈ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ OHÙN ÀÁRÍN OHÙN ÒKÈ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ OHÙN ÀÁRÍN OHÙN ÀÁRÍN ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ OHÙN ÌSÀLẸ̀ OHÙN ÀÁRÍN ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ OHÙN ÌSÀLẸ̀ OHÙN ÌSÀLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ Ohùn métẹ̀ta náà lè jẹjọ papọ̀ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń jeyọ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò OHÙN ÒKÈ OHÙN ÀÁRÍN OHÙN ÌSÀLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ORÍ KẸ́RIN ÀWỌN ÌGBÉSẸ̀ FONỌ́LỌ́JÌ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌFÁÀRÀ Nínú orí yìí ni a ti máa wo àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tí ó jẹyọ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì bí i àrànmọ́ àti oríṣìí àrànmọ́ tí ó wà ìpàrójẹ́ ìpajẹ fáwẹ́lì àti ìpajẹ kọ́ńṣónáǹtì àǹkóò fáwẹ́lì ÀRÀNMỌ́ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Nínú abala yìí ohùn tí fẹ́ gbé yẹ̀wò náà ni àrànmọ́ tó súyọ nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn oríṣìí àrànmọ́ tí a fẹ́ gbé yẹ̀wò náà ni àrànmọ́ iwájú àrànmọ́ ẹ̀yìn àrànmọ́ aláìfòró àrànmọ́ afòró ṣùgbọ́n ki a tó tẹ̀síwájú ó yẹ ki a mọ ohùn tí àrànmọ́ jẹ́ Gẹ́gẹ́ bí Oyèbádé ti ki àrànmọ́ ó ní; Ohùn tì onímọ̀ yìí ń gbìyànjú láti sọ náà ni wí pé nígbà tí ìró méjì tí ó jẹ́ nǹkankan náà tàbí tí ó yàtọ̀ si ara wọn bá dí ìró kan pé àrànmọ́ ti wáyé nìyẹn Ó tún wà tẹ̀síwájú nínú àlàyé tí o ń ṣe lórí àrànmọ́ ó ní Ohùn tí onímọ̀ yìí ń gbìyànjú láti sọ láti òkè náà ni pé ìró afàrànmọ̀ wà ìró agbàrànmọ̀ sì wà pẹ̀lú A lè wo bí àrànmọ́ ṣe rìn láti sọ irú àrànmọ́ tó wáyé ÀRÀNMỌ́WÁJÚ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÀRÀNMẸ́YÌN NÍNÚ Ẹ̀DÁ ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ará oko arọ́oko aróoko kú àbọ̀ káàbọ̀ káàbọ̀ irá ọ̀run iráòrun aọ̀ọ̀run omẹ eja ọmẹeja amẹẹja ka alẹ́ káalẹ́ káalẹ́ ÀRÀNMỌ́ ALÁÌFÒRÓ NÍNÚ Ẹ̀KA ÌKÁLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÀRÀNMỌ́ AFÒRÓ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÌPAJẸ KỌ́ŃṢÓNÁǸTÌ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ ìpajẹ kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n wón sábà máa ń pa kọ́ńṣónáǹtì r àti n jẹ́ r ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÌPAJẸ FÁWẸ́LÌ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìpajẹ fáwẹ́lì nínú èdè kan èyí máa ń wáyé nígbà tí fáwẹ́lì méjì bá fì ẹgbẹ̀kẹ̀gbẹ̀ ni àlàfo ọ̀rọ̀ Èyí túmọ̀ sí pé fáwẹ́lì lo gbọdọ̀ parí ọ̀rọ̀ àkókò tí fáwẹ́lì sì gbọdọ̀ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ kejì Nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ fáwẹ́lì ọ̀rọ̀iṣẹ́ ti ó jẹ́ àìránmípè nìkan ni a sábà máa ń pajẹ tí a sì máa ń dá ti ọ̀rọ̀ orúkọ sí ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÀNKÓÒ FÁWẸ́LÌ NÍNÚ Ẹ̀KA ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ fáwẹ́lì àìránmúpè méje ni wọ́n ni tí fáwẹ́lì u sì lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn A lè pín ànkóò fáwẹ́lì ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ si ọ̀wọ́ méjì báyìí Ọ́wọ́ Òwọ́ Àpẹẹrẹ ànkóò fáwẹ́lì ọ̀wọ́ nínú ìkaèdè Ìkálẹ̀ Ọ̀WỌ́ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ Àpẹẹrẹ ànkóò fáwẹ́lì ọ̀wọ́ nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ Ọ̀WỌ́ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ Nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ẹ̀wẹ̀ àwọn fáwẹ́lì ọ̀rọ̀ méjéèjì lè bá ara wọn siṣẹ́ nínú ọ̀rọ̀ Òwọ̀ àti ọ̀wọ́ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ÌGÚNLẸ̀ Tí a bà wo ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ìyàtọ̀ díẹ̀ náà ló wà nínú bí a ṣe ń pé àwọn ọ̀rọ̀ kan Ohùn tí ó tún fẹ́ jẹ́ ìyàtọ̀ ni pé àwọn kọ́ńsónáǹtì kan wà ti kò sí nínú Yorùbá àjùmọ̀lò ti ó sì wà ni ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àwọn kọ́ńṣónáǹtì bí i gh àti gw Bàkan náà kò sì kọ́ńṣónáǹtì ∫ nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ tí ó sì wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò Ìró fáwẹ́lì tí ó sì wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni ó wà ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Ohùn mìíràn tí ó jẹ ìyàtọ̀ tó fẹ́ wà láàárín ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò náà ni wí pé ní ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ wọ́n máa ń fi fáwẹ́lì u bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn bí àpẹẹrẹ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ Bákan náà wọ́n tún máa ń lo kọ́ńṣónáǹtì h fún s bí àpẹẹrẹ ÌKÁLẸ̀ YORÙBÁ ÀJÙMỌ̀LÒ ORÍ KARÙNÚN ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀ ÌFÁÀRÀ Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wi pé orí ti ó gbẹ̀yìn iṣẹ́ ìwádìí yìí ni a dé yìí Nínú orí yìí ni a ó ti ṣe àgbálọgbábọ̀ gbogbo ohun tí a ń sọ bọ̀ lórí iṣẹ́ àkànṣe yìí Nínú orí yìí ni a ó ṣe ìsọnísókí àbajáde ìwádìí àmúyẹ àti ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú ÌSONÍSÓKÍ ÀBỌ̀ ÌWÁDÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wi pé ohun tí iṣẹ́ àkànṣe yìí dálé ni fonọ́lọ́jì ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ tí a si ṣe àfiwé rẹ̀ pẹ̀lú Yorùbá àjùmọ̀lò nínú orí mẹrin tí iṣẹ́ yìí pin si Láti Ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ni ó ti farahàn pé ipò pàtàkì ni fonọ́lọ́jì wà láàárín gírámà èdè ní àgbáyé tí kò si yọ èdè Yorùbá sílẹ̀ náà ni a ṣe ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí fonọ́lọ́jì jẹ́ Gẹ́gẹ́ bí a ti kí fonọ́lọ́jì aní fonọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa ìsàpèjúwa àwọn ìróifọ̀ nínú èdè àti bátànì tí àwọn ìróifọ̀ ní nínú èdè bàkan náà a tun ki fònẹ́tíìkì torí pé àti fonọ́lọ́jì àti fònẹ́tíìkì àwọn méjèèjì ń bá ara wọ́n ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ gírámà A wo ohun ti èdè jẹ́ orírun èdè àbùdá èdè A si tun wo ohun ti ẹ̀ka èdè jẹ́ fún ra rẹ̀ àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ nítorí pé fonọ́lọ́jì ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ ni a ṣe Bákan náà a wo àwọn ìró tí a lè bà pàdé nínú ẹ̀dáèdè Ìkálẹ̀ èyí ni àwọn ìró kọ́ńṣónáǹtì ìró fáwẹ́lì àti ìró ohùn A yẹ àwọn ìgbèsẹ̀ fonọ́lọ́jì ti a lè rí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ Àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì bí i àrànmọ́ ìpàrójẹ́ ti a si wo ìyàtọ̀ tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ tí a si ṣe ìgínlẹ̀ lórí gbogbo rẹ̀ ÀMÚYẸ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé kò sí bí iṣẹ́ kan ṣe lè wà tí kò ní ní àwọn àmúyẹ kan tàbí òmíràn Lára àwọn àmúyẹ inú iṣẹ́ yìí ni pé ó mú kí a ní ìmọ̀ tó dájú nípa ìlú Ìkálẹ̀ ti ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ìpínlẹ̀ Òndó ó tun jẹ́ ki a mọ bí àwọn Ìkálẹ̀ ṣe ń pé ìró àti bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn ìró jáde Ohùn mìíràn tí ó tun ṣe pàtàkì ni pé ó jẹ́ ki a mọ àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà nínú àwọn ìró kan nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ àti Yorùbá àjùmọ̀lò o sí tun jẹ́ kí a mọ iye ìró kọ́ńṣónáǹtì àti ìró fáwẹ́lì tí ó wà nínú ẹ̀ka èdè Ìkálẹ̀ ó jẹ́ ki a mọ̀ wí pé ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ wà lára àwọn ẹ̀kaèdè tí wọ́n ní fáwẹ́lì àìránmúpè méje tí fáwẹ́lì u si lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn Lákòtán ó jẹ́ ki á mọ̀ ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè Yorùbá tí ó ṣe pàtàkì tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè tí ó gbájugbajà láàárín ilẹ̀ Yorùbá ÌMỌ̀RÀN FÚN ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé iṣẹ́ àkànṣe yìí dálé fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ ìmọ̀ràn mi fún oníṣẹ́ ìwádìí ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ìpele gírámà tí ó wà àwọn ìpele gírámà bí i mọfọ́lọ́jì síntáàsì oníṣẹ́ ìwádìí le ṣiṣẹ́ lórí àwọn wọ̀nyí nínú ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ tàbí nínú ẹ̀kaèdè mìíràn ÌKÁDÌÍ A ti gbìyànjú láti ṣe àgbéyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ nígbà tí a ti mọ ohun tí fonọ́lọ́jì èdè Yorùbá jẹ́ èdè Yorùbá àti ẹ̀kaèdè tí a sì ti yẹ àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà nínú Yorùbá àjùmọ̀lò àti ẹ̀kaèdè Ìkálẹ̀ wò Bákan náà a rí i wí pé ọ̀kan lára ẹ̀kaèdè Yorùbá tí a kò lè fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ni ẹ̀kaèdè yìí jẹ́ nínú èdè Yorùbá ÀKÓJỌ ORÚKỌ ÌWÉ Yorùbá Language Àjàyí Ẹ̀kọ́ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá Ẹ̀dáÈdè Lítíréṣọ̀ àti Àṣà IjebuOde Sebiotimọ Awóbùlúyì Yorùbá Èdè Ìperí Yorùbá Ìbàdàn Bámgbóṣé A Yorùbá Èdè Ìperí Yorùbá Bámgbóṣé A Fonọ́lọ́jì àti Gírámà Yorùbá Ìbàdàn Odùyẹmí SO Àfiwé Fonọ́lọ́jì Ẹ̀kaÈdè Akúrẹ́ àti Yorùbá Àjùmọ̀lò Iṣẹ́ Àṣekágbá Fún Gbígba Oyè Bíi Eè Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè àti Èdè Ilẹ̀ Nàìjíríà Olúnládé T Èdè Yorùbá àti Ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè Oyèbádé Oyè T Mọ́lọ́jì