diff --git "a/yorubaCorpus/YcorpussssxxxqqqqsL_0.txt" "b/yorubaCorpus/YcorpussssxxxqqqqsL_0.txt" new file mode 100644--- /dev/null +++ "b/yorubaCorpus/YcorpussssxxxqqqqsL_0.txt" @@ -0,0 +1 @@ +ỌRỌ ÌYÀNJÙ Odò to ba gbagbe orisun rẹ, gbigbe lo ma ngbe Éyin ti ájà bá kọkọ ni, ónilè ẹ lò fi n gè jẹ Ẹyin ọmọ Odùduwà ẹjẹ ki a ran rawa létí wípé Ẹni tólèdè lóni ayé ibi ti wọn ti nsọ Mo bẹ yin ẹ maṣe jẹki a tara wa lọpọ nítorí náà ẹ maṣe jẹki èdè Yorùbà parẹ Èdè ti a kọ silẹ, ti a ko sọ, ti a ko fi kọ ọmọ wa, piparẹ ni yio parẹ Ẹjẹ ki a gbiyanju lati ṣe atunṣe nípa sísọ èdè Yorùbà botiyẹ kasọ lai si idaru idapọ pẹlu èdè miran Yorùbá lọkùnrin ati lobirin ẹ ranti wipe Odò to ba gbagbe orisun rẹ, gbigbe lo ma ngbe Lágbára Ọlọrun, aoni tajo sọnu sajo o, ao kere oko délé o. Àṣẹ Ọpọlọpọ oriṣiriṣi ounjẹ Yorùbá nparẹ lọ, nípàtàkì larin awọn to ngbe ìlú nla Òwe Yorùbá ni Ki àgbàdo to de ilẹ aye, adìyẹ njẹ, adìyẹ nmu Itumo eyi nipe ki a to bẹrẹ si ra ounjẹ latokere, a nri ounjẹ ilẹ wa jẹ Awọn to ngbe ilu nla bi ti Èkó ko ri aye lati se ọpọlọpọ ounjẹ ilẹ wa, èyí ko jẹki àlejò mọ wipe Yorùbá ni oriṣiriṣi ọbẹ, ounjẹ ati ìpanu Ni ọpọ ọdun sẹhin, irẹsi ki ṣe ounjẹ ojojumọ ṣugbọn fun awọn ọmọ igbalode, Irẹsi Burẹdi ati Indomie ti di ounjẹ Ọpọlọpọ ko ti ẹ fẹ jẹ ounjẹ ibilẹ bi awọn ounjẹ òkèlè Iyán, Ẹba, Láfún àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ti a ba ṣakiyesi, ọpọ ọmọ to dagba si Èkó, ko mọ wipe Yorùbá ni ju ọbẹ ata ati ẹfọ lọ Ọbẹ ata lo yá lati fi jẹ irẹsi, nítorí ọpọ ninu awọn ọmọ wọnyi le jẹ irẹsi lojojumọ, larọ, lọsan ati lalẹ Ni ìlú Èkó, sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ko jẹ ki obi tètè délé lẹhin iṣẹ ojọ wọn, ẹlo miran ti ji kuro nílé lati bi agogo mẹrinabọ lai pada sílé titi di agogo mẹwa alẹ nígbàtí awọn ọmọ tisùn Nítorí èyí ọpọ òbí ko ri aye lati se ounjẹ Yorùbá Àìsí ina manamana dédé tun da kun ifẹ si ounjẹ pápàpá Ìyàlẹnu ni wipe ọpọ awọn ti ówà l'Okeokun ngbe ounjẹ Yorùbá larugẹ ju awọn ti ówà ni ilé lọ pàtàkì ni ilu nla Oṣeṣe pe bi iná manamana ba ṣe dédé ounjẹ Yorùbá yio gbayi si, nítorí awọn òbì ma le se oriṣiriṣi ounjẹ pamọ Ẹjọwọ ẹ maṣe jẹ ki a fi ounjẹ òkèrè dipo ounjẹ ilẹ wa, okùnfà gbèsè ni ÌRÒYÌN ÌJÌ NLA JÀ NI ÌBÀDÀN Òjò ati ìjì bẹrẹ ni arọkutu ọjọ ajé, ọjọ kejidinlogun oṣu keji ọdún ẹgbẹwa le mẹtala Ìjì naa ba ílé ati ọna jẹ rẹpẹtẹ ni ìlú Ìbàdàn Òwe Yorùbá sọ wipe Ogun àsọ tẹlẹ ki parọ to ba gbọn O ṣeni lanu wipe ko si àsọ tẹl tabi ipalẹmọ fún ará ìlú ati ijọba Iyalẹnu ni wipe lati ọpọ ọdun ti ìjì àti àgbàrá lati odò Ògùnpa ti mba ilé ati ọna jẹ lọdọdun, Ìjọba Ọyọ ko ti ri ogbọn kọ lati da ẹkun ati ibanujẹ ti iṣẹlẹ yi nda silẹ A NGBA ÒRÒMỌDÌYẸ LỌWỌ IKÚ O NI WỌN O JẸ KI OHUN LỌ ATAN LỌJẸ A le lo òwe yi lati kilọ fun ẹni to fẹ lọ si Òkè-òkun lọna kọna lai ni ase tabi iwe ìrìnà Bi ẹbi, ọrẹ tabi ojúlùmọ to mọ ewu to wa ninu igbesẹ bẹ ba ngba irú ẹni bẹ niyanju, a ma binu wipe wọn o fẹ ki ohun ṣoriire Bi ounjẹ ti pọ to l'atan fun oromọdiyẹ bẹni ewu pọ to Bi ọna ati ṣoriire ti pọ to ni Òkè-òkun bẹni ewu ati ibanujẹ pọ to fun ẹniti koni aṣẹ ìrìnà Ọpọlọpọ nku sọna, ọpọ si nde ọhun lai ri iṣẹ, lai ri ibi gbe tabi lai ribi pamọ si fun Òfin Lati pada si ile a di isoro nítorí ọpọ ninu wọn ti ta ile ati gbogbo ohun ìní lati lọ oke okun Bi iru ẹni bẹ ṣe npe si l'Òkè-òkun bẹni ìtìjú ati pada sile se npọ si A le ka si ounjẹ osan ỌJỌ GBOGBO NI TI OLÈ, ỌJỌ KAN NI TOLÓHUN Ní ọjọ Ẹti ọjọ keji lelogun oṣu keji ọdún yi, Ẹrọ amóhùn máwòrán Iluọba tu asiri ọmọkùnrin kan ti o ni iwe ijẹri irina ọmọ Naijeria ni oruko ọtọtọ mẹta ti o fi nlu ìjọba ní jìbìtì gba iranlọwọ ti ko tọ si O ti gba owó rẹpẹtẹ ki wọn to ri mu Ni Ìlú Ọba Ìjọba pese ilé fún awọn abirùn ati aláìní ti o jẹ ọmọ onilu ati iranlọwọ miran lati mu ayé dẹrùn fún wọn Àwọn àjòjì ti o fi èrú ati irọ gba àwọn iranlọwọ yi, wọn a dẹ tún fi ma yangan titi ọjọ ti olóhun yio fi muwọn Irú iwa burúkú bi ka fi èrú gba ohun ti ko tọ wọnyi mba orúkọ jẹ Ẹ jẹ ki a fi owé Yorùbá to wipe Ọjọ gbogbo ni tolè, ọjọ kan ni tolóhun se ikilo fun iru awọn oníjìbìtì bẹ ere jibiti, nítorí bi o ti wu ko pẹ to, ọjọ kan ọwọ òfin a ba iru àwọn bẹ Nígbàtí wọn ba ri wọn mu, wọn a ko ìtìjú ba orúkọ idile ati ìlú wọn Ìròyìn ikú Olóògbé Chinua Achebe, ògúnná gbongbo ninu Olukọwe ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú àti àgbáyé kàn ni ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejì lélógún, oṣ̀u kẹta ọdún ẹgbẹ̀rún méjì le mẹ́tàlá Ọmọ ọdún méjì le lọgọrin ni Olóògbé Chinua Achebe nígbà ti o pa ipòdà Ìkan nínú ìwé ti Olóògbé Chinua Achebe kọ Nkan túká di kíkà fún àwọn ọmọ ilé-ìwé lati ilẹ̀ ènìà dúdú títí dé Òkè-òkun Títí di àsìkò yi, ìwé na ngbayi si ni, nítorí wọn ti túmọ̀ ìwé yi sí èdè oriṣiriṣi Àdánù nla ni ikú Olóògbé Chinua Achebe jẹ́ fún Naijeria, ìlú aláwọ dúdú àti gbogbo Olùkọ̀wé lagbaye Olórí Òṣèlú Venezuela Hugo Chavez, pa ipò dà ní ọjọ́ ìṣẹ́gun ọjọ́ karun oṣù kẹta ọdún ẹgbẹ̀rún méjì lémẹ́tàlá Nígbà ayé ologbe yi, ó fa àríyànjiyàn, bí ó ti fẹ́ràn àwọn ìlú kan bẹ lo korira àwọn ìlú míràn Lati ìgbà tí ìròyìn ikú rẹ̀ ti kan, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni gbogbo àgbáyé ti nsọfọ bẹni àwọn kan nfi àibìkítà han Eleyi fihan wípé ohun tí ó kọju sí ẹnìkan ló kẹ̀hìn sí ẹlòmíran Ìdábẹ́ jẹ ìkan nínú àṣà Yorùbá tí ólòdì si ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin Gẹ́gẹ́bí ìtàn ìdábẹ́, Yorùbá ndabẹ fún ob̀nrin ní àti ìkókó títí dé ọmọ ọdún kan, nwọn ní ìgbàgbọ́ wipe yio da ìṣekúṣe dúró lára obìnrin Tiítí òde òní, àṣà Yorùbá ṣì nfi ìyàtọ̀ sí àárín obìnrin ati ọkùnrin, ní títọ́ àti ní àwùjọ Gẹ́gẹ́bí Olókìkí Oló́rin Jùjú Ebenezer Obey ti kọ́ lórin Àwa ọkùnrin le láya mẹ́fà, kò burú, ọkùnrin kan ṣoṣo lọba Olúwa mi yàn fún obìnrin Wọ́n ṣe àlàyé àlébù tí àṣà burúkú yi jẹ́ fún àwọn obìnrin tí wọ́n bá dábẹ́ fún, ara àlébù bi ọmọ lè kú ikú ẹ̀jẹ̀ dídà, ìṣòro tí irú ẹni bẹ bá fẹ tọ̀, ìsòro ní ìgbà ìbímọ àti bẹbẹ lọ Ìjọba ti pèsè owó púpọ̀ lati fi òpin sí àṣà ìdábẹ́ ní Ìlú-Ọba Bí a ti nṣe àjọ̀dún Ọjọ́ áwọn Obìnrin lagbaaye, oṣe pàtàkì kí Yorùbá ní ilé àti ní àjò, di àṣà tí ó bùkún àwọn ọmọ mú, kí a sì ju àṣà tí ó mú ìpalára dání dànù Ẹ̀kọ́ áti àbójútó lati ọ̀dọ́ òbí ló lè dá ìṣekúṣe dúró, ki ṣe ìdábẹ́ Yorùbá nί Bί a bá ránni nί iṣẹ ẹrú, a fi tọmọ jẹ Eleyi fi Ìwà ìkà ọmọ enia sί ọmọ enia han Ọlọpa South Africa ṣi àṣẹ ti wọn nί lὸ, wọn rán wọn niṣe ẹrú, wọn o fi tọmọ jẹ Bí a ti nṣe ní ilé wa, ewọ ibòmíì A kì dàgbà jẹ Òjó Òjó, Dàda, Àìná, Táíwò, Kẹhinde ati bebe lo je orúkọ amu tọrun wa Pípa orúkọ Ilé-ìwé gíga ni Akoka, ilu Èkó da lẹhin aadọta ọdún dàbí ìgbà ti a sọ arúgbó lorukọ àmú tọrun wa Apẹrẹ ẹni ti ki ṣe ibeji ko le pa orúkọ da si orúkọ àmú tọrun wa A dupẹ lọwọ Olórí Ìlú Goodluck Jonathan to gbọ igbe awọn ènìyàn lati da orúkọ Ilé-ìwé Gíga ti o wa ni Akoko ti Ilu Èkó pada gẹgẹbi Olukọagba Jerry Gana, ti kọ si ìwé ìròyìn ni ọjọ Ẹti, oṣù keji ẹgbaa le mẹtala ÒKÚ NSUKUN Ò̀KÚ, AKÁṢỌLÉRÍ NSUKUN ARA WỌN Ọmọ ọdún mẹtadinladọrun ni nígbàtí ó dágbére fún ayé ni oṣù kẹrin ọjọ kẹjọ, ọdún ẹgbẹ̀rúnméjìlémẹ́tàlá Yorùbá ni Òkú nsukun òkú, akáṣolérí nsukun ara wọn ìtumọ̀ èyí ni wípé kò sẹ́ni tí kò ní kú, olówó, aláìní, ọmọdé, arúgbó, Òṣèlú, Ọba àti Ìjòyè á kú tí àsìkò bá tó, nítorí náà, ẹni to sunkun, sunkun fún ara rẹ, ẹni tó mbinu, mbinu ara rẹ nítorí, ẹni tó kú ti lọ Ojúọjọ́ dára, ètò ìsìnkú náà lọ dédé láìsí ìdíwọ́ Ìgbéyàwó ìbíle ní Ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ àsìkò ti ẹbí ọkọ àti ì̀yàwó ma nparapọ A lè ṣe gbogbo ètò ìgb́eyàwó ìbílẹ̀ ni ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ púpọ̀ fún àpẹrẹ mọ̀mí-nmọ̀ẹ lọjọkan ati idana lọ́jọ́ keji tàbi ọjọ miran Ní ayé àtijọ́, nígbàtí Yorùbá ma nṣe ayẹyẹ níwọ̀ntúnwọ̀sín, ilé ẹbí tàbi ọgbà bàbá àti ìyá ìyàwó ni wọn ti nṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n láyé òde òní, àyè ọ̀tọ̀ bi ilé ìlú, pápá ìṣeré, ilé àlejò àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n nlo Àṣà gbígba àyè ọ̀tọ tógbòde bẹ̀rẹ̀ nítorí àwọn adigun jalè àti àwọn ènìyàn burúkú míràn ti o ma ndarapọ pẹ̀lú àwọn àlejò tí a pè sí ibi ìyàwó lati ṣe iṣẹ́ ibi Owó púpọ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ma nfi gba à̀yè ibi ṣíṣe ìyàwó Bí òbí ba ti lọ́lá tó ni wọn ma náwó tó, nítorí ìdùnnú ni fún òbí pé a tọ́mọ, wọ́n gbẹ̀kọ́, wọn fẹ di òmìnira lati bẹ̀rẹ̀ ẹbí tíwọn, ṣùgbọ́n àṣejù ati àṣehàn ti wa wọ́pọ̀ jù Nítorí ìnáwó ìgbéyàwó, ilé ayẹyẹ pọ̀ju ilé ìkàwé lọ láyé òde òní Kí ṣe bi a ti náwó tó níbi ìgbéyàwó lo nmu àṣeyorí ba ọkọ àti ìyàwó, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ntuka láìpẹ́ lẹ́hin ariwo rẹpẹtẹ yi Yorùbá ni A ki fọlá jẹ iyọ̀, nínú ìṣẹ layika ni ilẹ̀ Aláwọdúdú, ó yẹ ki a ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó níwọ̀ntúnwọ̀nsìn Ẹ fojú sọ́nà fún ètò ìgbéyàwó ibilè Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, ọwọ́ ni a fi njẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Yorùbá, nítorí kò si ṣíbí tó dára tó ọwọ́ lati fi jẹ oúnjẹ òkèlè bi iyán, èyí jẹ kó ṣe pàtàkì lati fọ ọwọ́ mejeji lẹ́hìn oúnjẹ Fífọ ọwọ́ kan kòlè mọ́ bi ka fọ ọwọ́ mejeji Ọ̀rọ̀, ọ̀tún wẹ òsì, òsì wẹ ọ̀tún, lọwọ́ fi nmọ wúlò lati gba àwọn ènìà níyànjú wípé àgbájọwọ́ láàarín ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ará ìlú lérè Yorùbá ni Àgbájọ ọwọ́ la fi nsọya, ajẹjẹ ọwọ́ kan ko gbe ẹrú dórí, ọmọ Yorùbá nílélóko, ẹ jẹ́kí a parapọ̀ tún ílú ṣe Òkìkí ikú Ìyáàfin Margaret Thatcher, obìnrin àkọ́kọ́ lati dé ipò Olórí Òṣel̀ú Ìlúọba kàn ní oṣù kẹrin, ọjọ́ kẹjọ, ọdún ẹgbẹ̀rúnméjìlémẹ́tàlá Orin yi ba ìgbà ayé Olóògbé Ìyáàfin Margaret Thatcher mu Gẹ́gẹ́bí Obìnrin àkọ́kọ́ tó di Olórí Òṣèlú Ìlúọba, ó ṣe ìwọ̀n tó lèṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ìlù rẹ̀ Ọ̀rọ̀ tó wọ́pọ̀ ni Lẹ́hìn ọkùnrin tó ṣorire, obìnrin wa nbe, ṣùgbọ́n wíwo ìgbésí ayé àwọn og̀bójú obìnrin bi Olóògbé Fúrnmiláyọ̀ Ransome Kútì àti Olóògbé Margaret Thatcher fihàn wípé lẹ́hìn obìnrin tó bá́ ṣe orire, ọkùnrin wa nbẹ, ọkọ wọn dúró tìwọn gbọingbọin, èyí fi ọkàn àwọn aṣájú nínú àwọn obìnrin àgbáyé yi balẹ̀ lati tọ́jú àwọn ọmọ pẹ̀lú iṣẹ́ Òṣèlú tí obìnrin kò wọ́pọ̀ lásìkò tiwọn Sùn re o, Ìyáàfin Thatcher Yorùbá ní Bí ewé bá pẹ́ lára ọṣẹ, á dọṣẹ,ọ̀rọ̀ yí bá ẹgbẹ́ Yorùbá ni Ìlúọba mu pàtàkì àwọn ti o ngbe ni Olú Ìlúọba Títí di bi ọgbọ̀n ọdún sẹhin, àti rí oúnjẹ Yorùbá rà ṣọ̀wọ́n Ní àpẹrẹ, àti ri adìẹ tó gbó rà lásìkò yi, à fi tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá lọ si òpópó Liverpool, ṣùgbọ́n ní ayé òde òni, kòsí agbègbè ti ènìà kò ti lè rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Yorùbá ra Lati bi ogún ọdún sẹ́hin, Yorùbá ti pọ̀si nidi àtẹ oúnjẹ títà ni Olú Ìlúọba Àwòrán àwọn ọjà wọnyi a bẹrẹ pẹ̀lú, Ọja Dalston àti Kingsland Ẹ fojú sọ́nà fún àwọn ọja yókù Ọ̀rọ̀ Yorùbá yi ba ìjọba Ìlúọba àti àwọn ará ìlú wi Ìjọba njaya nítorí owó ti o nwọle kò kárí owó lati ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀tọ́ ti àwọn ará ìlú nri gbà Àwọn ti o si ngba ẹ̀tọ́ lọ́dọ̀ ìjọba njaya nítorí, ẹ̀tọ́ ti Ìjọba ndiku yio mu ìnira bá wọn nítorí ẹ̀dín owó yi bọ́sí àsìkò ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ àti ohun ìtura míràn Díẹ̀ nínú àwọn àtúnṣe yi ni ìdérí owó ìrànlọ́wọ́ si poun mẹrindinlọgbọn lọ́dún fún ìdílé, yíyọ owó fún yàrá tó ṣófo, àtúnṣe fún Ilé Ìwòsàn lapapọ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Yorùbá ni Kòsọ́gbọ́n tí o lèda, kòsíwà tí o lèhù tí o lè fi tẹ ayé lórùn, bí ọ̀pọ̀ ti nyin ìjọba bẹ́ẹ̀ni ọ̀pọ̀ mbu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu àtúnṣe wọnyi wípé Ìjọba ngba lọ́wọ́ aláìní fún àwọn tóní Yorùbá ní Ẹnití Ọlọrun kò dùn nínú, tó nla ṣúgà, jẹ̀díjẹdí ló ma pá Ọ̀rọ̀ Yorùbá yi ṣ̀e àtìlẹhìn fún iwadi tó fihàn wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ìrẹ̀wẹ̀sì mbaja ma mu ọtí àti jẹ oúnje ọlọra, ti iyọja tàbí tí iyọ̀ ìrèké pọ̀ nínú rẹ Oúnje dídùn àti ọtí mímu kò lè mú ìrẹ̀wẹ̀sì kúrò tàbí fa ìdùnnú, ṣùgbọ́n àyípadà ọkàn sí ìwà rere àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọrun ló lè mú inú dùn Ẹkú ọdún Ajinde o, ẹ ma jẹ́un ju, Jésù ku fun ẹlẹ́sẹ̀ àti aláìní, nítorí náà ti ẹ ba ri jẹ, ẹ rántí áwọn ti ko ri Yorùbá ni ajọjẹ kò dùn bẹni kan o ri Nínú ìwé ìròyìn Vanguard, ti ọjọ́ Àìkú, oṣù kẹta, ọjọ́ , ọdún kẹrinlélógún, Ẹgbaalémétàlá, Olùkọ́ àgbà ti Èdè ati Àṣà, Akínwùnmí Ìṣọ̀lá, kébòsí wípé èdè Yorùbá àti èdè abínibí miran le parun ti a ko bá kíyèsára Ìkìlọ̀ yí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún akitiyan Olùkọ̀wé yi lati gbé èdè àti Yorùbá ga lórí ẹ̀rọ Ayélujára Àwọn Òṣèlú tó yẹ ki wọn gbé èdè ìlú wọn lárugẹ n dá kún pí pa èdè rẹ Òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá ko fi èdè na ṣe nkankan ni Ilé-òsèlú, wọn o sọ́, wọn ò kọ́, wọn ò ká Àwọn Òṣèlú ayé àtijọ́ bi Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólówọ̀, Olóyè Ládòkè Akíntọlá, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ gbé èdè wọn lárugẹ bi ó ti ẹ̀ jẹ́ wípé wọn kàwé wọn gboyè rẹpẹtẹ Yorùbá ní Àgbà kì í wà lọ́jà kórí ọmọ tuntun wọ́ Ó yẹ ki àwọn àgbà kọ́ ọmọ lédè, kí à si gba àwọn ọmọ wa níyànjú wípé sí sọ èdè abínibí kò dá ìwè kíkà dúró ó fi kún ìmọ̀ ni Yorùbá ní Ẹ̀bẹ̀ la mbẹ òṣìkà pé kí ó tú ìlú rẹ ṣe, A bẹ àwọn Òṣèlú́ Ilẹ̀ Yorùbá ni agbègbè Èkìtì, Èkó, Ògùn, Ondó, Ọ̀ṣun àti Ọ̀̀yọ́, lati ṣe òfin mí mú Kíkọ àti Kíkà èdè Yorùbá múlẹ̀ ní gbogbo ilé ìwé, ní pàtàkì ní ilé-ìwé alakọbẹrẹ ilẹ̀ Yorùbá nítorí ki èdè Yorùbá ma ba a parẹ́ Ewédú jẹ ikan nínú ọbẹ̀ Yorùbá tó wọpọ ni agbègbè Ọ̀yó, Ọ̀sun, Ògùn gẹ́gẹ́bi ilá ti wọ́pọ̀ ni agbègbè Ondo àti Èkìti Fún ẹni tó́ nkanju, ilá yára láti sè ju ewédú lọ, nítorí àsìkò lati tọ́ ewédú ati lati fi ìjábẹ̀ ja, pẹ ju rírẹ àti síse ilá lọ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ko ríra pe wọn nfi ìgbálẹ se ọbẹ̀ lai mọ wípé ìjábẹ̀ kò wà fún ilẹ̀ gbígbá ọwọ̀ kukuru tuntun ti o wa fún ewédú Ni ayé ìgbàlódé yi, dípò ìjábẹ̀, a le lọ ewédú nínú ẹ̀rọ ata ìgbàlode fún bi iṣeju kan, eleyi din àsìkò síse ewédú kù si bi ọgbọn ìṣéjú fún ewédú ọbẹ̀ enia mẹwa Ewédú̀ dùn pẹ̀lú gbẹ̀gìrì tàbi ọbẹ̀ ata lati fi jẹ Ẹ̀kọ, Àmàlà, Láfún àti ounjẹ òkèlè yókù bi Ẹ̀bà, Iyán àti bẹẹbẹ lọ Lẹhin ọdún mẹwa, ìdájọ bẹrẹ fún gbọmọgbọmọ to ji àwọn obinrin mẹta pamọ́ Nígbàtí ọwọ òfin tẹ Ariel Castro, gbogbo agbára to fi njẹ àwọn obinrin wọnyi niya di òfo Ariel Castro nṣe ojú aanu bi ẹni pé ki ṣe ohun lo ṣe iṣẹ́ ibi fún ọdún mẹwa o le díẹ̀ Àdúrà Yorùbá́ ni Ki Oluwa gbani lọ́wọ́ ẹni tó nṣọni, ti a ko ṣọ, àdúrà yi gbà fún àwọn obinrin mẹta ti gbọmọgbọmọ ti jígbé lati bi ọdún mẹwa sẹhin Ìkan nínú àwọn ọmọ obinrin yi bí ọmọ ti o ti pe ọdún mẹfa sínú àtìmọle yi Ìbànújẹ́ tí kò lafi we ni ki ọmọ sọnu Gẹgẹbi ọrọ Yorùbá Ọmọ́kú san ju ọmọ sọnu lọ pàtàkì lára ìyá ọmọ, ìrònú ọmọ sọnu pa ìya ikan nínú àwọn obinrin mẹta yi, o ṣeni laanu wípé kò rí ọjọ́ ayọ̀ ìtúsílẹ̀ nínú ìdè tí Ariel Castro fi àwọn obinrin yi si Ìyanu ni wípé wọn jade laaye, nítorí ọpọlọpọ lo nsọnu ti wọn ki ri òkú tàbí aaye wọn Ìròyìn pé àwọn Ọlọpa tú àwọn obinrin mẹta yi silẹ lati ilé ẹni tó gbé wọn dè jade ni ọjọ Ajé, oṣù karun, ọjọ́ kẹfa, ọdún ẹgbẹ̀rúnméjìlemẹtala Òwe Yorùbá yi wúlò lati juwe òye àgbàlagbà lati wo ẹ̀hìn fún ẹ̀kọ́ nínú ìrírí tó ti kọjá lati yanjú ọ̀ràn tó ṣòro nígbàtí ọmọdé tí kò rí irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ lati kọ́ ọgbọ́n, má nwo iwájú Ọ̀rọ̀ Yorùbá miran ni Ẹni tó jìn sí kòtò, kọ ará yókù lọ́gbọ́n Nitotọ ọ̀rọ̀ miran sọ wípé Ìṣòro ni Olùkọ́ tó dára jù, ṣùgbọ́n dí dúró kí ìṣòro jẹ Olukọ fún ni lè fa ewu iyebíye, nítorí náà ó dára ká kọ́ ọgbọ́n lati ọ̀dọ̀ àgbà Ọlọ́gbọ́n ma nlo ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n lati yẹra fún ìṣubú Ní àsìkò ẹ̀rọ ayélujára yi, òwe Bí ọmọdé bá ṣubú á wo iwájú, bí àgbà bá ṣubú á wo ẹ̀hìn ṣi wúlò fún àwọn ọmọdé tí ó lè ṣe àṣàyàn lati fi etí si àgbà, kọ́ ẹ̀kọ́, tàbí ka àkọsílẹ̀ ìrírí àgbà nínú ìwé tàbí lórí ayélujára lati yẹra fún àṣìṣe, kọ́ ibi tí agbára àti àilera àgbà wà fún lílò lọ́jọ́ iwájú Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ wípé ọwọ́ ọmọde ko to pẹpẹ, tagbalagba ko wọ̀ kèrègbè, èyí tí a lè túmọ̀ sí wípé, ọmọdé kò ga to pẹpẹ láti mú nkan tí wọn gbé si orí pẹpẹ, bẹni ọwọ́ àgbàlagbà ti tóbi jù lati wọ inú akèrègbè lati mu nkan, nítorí náà àgbà̀ lèlo ìrànlọ́wọ́ ọmọdé Ní ayé, oníkálukú ló ní ohun tí wọ́n lè ṣe Àwọn nkan wa ti àgbàlagbà lè ṣe bẹ́ẹ̀ni ọpọlọpọ nkan wa ti ọmọdé lè ṣe Láyé òde òní, ọmọdé le gbójúlé àgbàlagbà, ṣùgbọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbàlagbà gbójúlé ọmọdé láti kọ́ lílò ẹ̀rọ ayélujára Ò̀we yi fi èrè ifọwọsowọpọ laarin ọmọdé àti àgbà han nítorí kò sẹ́ni tí kò wúlò Ọmọ ìyá méjì ki réwèlè, Yorùbá ma nlo ọ̀rọ̀ yi nígbàtí ọmọ ìyá méjì ba ko àgbákó tó la ikú lọ Irú ìsẹ̀lẹ̀ tó kó ìpayà ba gbogbo ènìà bayi ki ṣe ijamba lásán ṣù́gbọ́n àwọn ìyá méjì Tsarnev, ni wọn tọ́ka si fún iṣẹ́ ibi tó ṣẹlẹ̀ ni oṣù kẹrin ọjọ kẹdogun nibi ere ọlọnajijin tí wọn sá ni Boston Kikọ ọmọ lati ṣe Ọmọlúàbí jẹ́ ohun ti àwọn òbí ayé àtijọ́ ndù ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí ayé òde òní tó ndu owó lati kó ọrọ̀ jọ ju wípé ká kọ́ ọmọ lọ Kíka ọrọ ìfojúkojú nínú ìwé ìròyìn fihàn wípé ẹ̀kọ́ ti ìyá àti bàbá bá kọ́ ọmọ ni kékeré wúlò fún ẹbí àti ará lọ́jọ́ iwájú Ẹkọ ti Gómìnà Fáṣọlá gbà lọ́wọ́ òbí wúlò fún ẹbí, ará àti ìlú Èkó Bí orí bá pẹ́ nílẹ̀ á dire, bi o tiẹ jẹ wípé Gómìnà Fáṣọlá kò fẹ́ ṣe iṣẹ́ Òṣèlú, orí darí rẹ síbẹ̀ Òwe Yorùbá ni Orí olókìkí kò jẹ́ asán, wọ́n nkigbe ẹ nílé, wọ́n nkigbe ẹ́ logùn, nitòótọ Gómìnà Fáṣọlá gbìyànjú fún ìlú Èkó, ṣùgbọ́n omi pọ̀ ju ọkà lọ Góm̀nà, ẹ kú orire adọọta ọjọ́ ìbí, orire naa dalẹ́, ẹ̀mí ọlá á gùn lati ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ìbí láyé o. Àṣẹ Èkó ò ní bàjẹ́ o! Ni ọjọ Ẹti, oṣù kẹfa ọjọ keje, ọdún ẹgbẹrunméjìlemẹtala, Adájọ́ ṣe ìdájọ ẹ̀wọ̀n gbére fún Ọpẹmipọ Jaji, ọmọ ọdún méjìdínlógún fún dídó fàdíya Laipẹ yi, Michael Adébọ́lájọ ati Michael Adébọ̀wálé wá si Iléẹjọ́ fún ẹ̀sùn apànìyàn Ìròyìn burúkú yi ko ti lọ lẹ̀, nígbàtí ìròyìn ìdájọ ẹ̀wọ̀n gbére fún Ọpẹmipọ Jaji tún jade Kíló nṣẹlẹ Yorùbá ni àgbà kì wá lọ́jà ki orí ọmọ tuntun wọ́ Àsìkoì tó ki àgbàgbà Yorùbá ni Ìlúọba parapọ̀ lati ṣe iwadi ohun tó fa àwọn ọmọ tíwọ́n bẹ̀rẹ̀ si hùwà burúkú wọnyi láàarín àwon ọ̀dọ́ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Yorùbá ló nṣe dáradára ní ilé àti àjò tí a kò gbọ́ ìròyìn wọn Yorùbá ni Ẹni jalè ló bọmọ jẹ, ìròyìn iṣẹ́ rere ki tàn bi irú ìròyìn iṣẹ ibi ti Michael Adébọ́lájọ àti Michael Adé́bọ̀wálé tó kárí ayé Ó yẹ ki Ìjọba àti gbogbo Yorùbá pa ẹnu pọ lati bá oníṣẹ ibi wi nítorí gẹ́gẹ́bí òwe Yorùbá Ẹrú kan ló́ mú ni bu igba ẹrú Àṣà ilẹ̀ Yorùbá títí di àsìkò yi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin ma nni ìyàwó púpọ́ wọn si ma mbi ọmọ púpọ̀, wíwọ irú aṣọ kan naa fun ṣíṣe ma nfi ẹbi han Aṣọ ẹbí bẹ̀rẹ̀ nípa ki ọkọ àti ìyàwó dá irú aṣọ kan nigba ìgbéyàwó àti wíwọ irú aṣọ kan naa lẹhin ìgbéyàwó lati fi han wípé wọn ti di ara kan Bàbá ma nra aṣọ irú kan naa fun àwọn ọmọ nítorí ó dín ìnáwó kù láti ra irú aṣọ kan naa fún ọmọ púpọ̀ nípa ríra ìgàn aṣọ ju ríra ni ọ̀pá Aṣọ ẹbí tún wa fún ẹbí àti ọmọ oloku, ìyàwó ṣíṣe, ẹgbẹ́ ìlú àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Nígbàtí wèrè ko ti wọ àṣà aṣọ ẹbí, ẹnití o ṣe ìyàwó, ṣe òkú, sọ ọmọ lórúkọ àti ṣiṣe yoku ma npe aṣọ ni Kò kan dandan ki ènìá ra aṣọ tuntun fún gbogbo ṣíṣe, fún àpẹrẹ, aṣọ funfun ni wọn ma sọ wípé ki àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wọ̀ fún òkú ṣíṣe, aṣọ ibilẹ̀ bi aṣọ òfi àti àdìrẹ fún ìgbéyàwó Ẹbí ìyàwó le sọ wípé ki ẹgbẹ́ wọ aṣọ aláwọ ewé lati ba ohun yọ ayọ ìgbéyàwó, ki ẹbí ọkọ ni ki àwọn ẹgbẹ́ wọ àdìrẹ ti wọn ti ra tẹ́lẹ̀ fún ìgbéyàwó Lati bi ogoji ọdun sẹhin, lẹhin ti ìlú ti bẹ̀rẹ̀ si naa owó epo, àṣejù ti wọ àṣà aṣọ ẹbí rírà Àṣà aṣọ ẹbí ti káári ìlú kọjá ile Yorùbá si gbogbo Nàíjíríà Ọ̀pọ̀lọpọ̀ a ma jẹ gbèsè nítorí àti ra aṣọ ẹbí, pàtàkì ni Ìlúọba ti àwọn miran ti nṣiṣẹ àṣekú lati kó irú owó bẹẹ si aṣọ ẹbí, àwọn miran á kó owó oúnjẹ àti owó ilé ìwé lórí aṣọ ẹbí Ìlú ńbàjẹ si, kò síná, kò sómi, ìṣẹ́ pọ, aṣọ ẹbí ko le mu ìṣẹ́ kúrò tàbi sọ ẹnití o jẹ gbèsè láti ra aṣọ ẹbí di ènìyàn nla nítorí Aṣọ nla, kọ lènìyàn nla – Yorùbá ni ilé lóko, ẹ dín wèrè aṣọ ẹbí kù Ọ̀rọ̀ Yorùbá ní Ẹni tó Lórí kò ní Fìlà, Ẹni tó ní Fìlà kò Lórí Tani eni Ẹni tó Lórí ti kò ní Fila Enití gbogbo àyè wà fún lati ṣe nkan nla bi ka kọ́ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ lati pèsè àyè à́ti ohun améyédẹrùn fún ìlú àti ará ìlú tí kò ló àyè yi Tani Ẹni tí ó ni Fìlà tí kò Lórí Eni tí ìlú tàbí òbí ti pèsè àyè àti gbogbo ohun améyédẹrùn fún láti lè kọ́ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ ṣùgbọ́n tó kọ̀ láti kọ ẹ̀kọ́ tàbi kó kọ́ iṣẹ́ ọwọ Kò sí ẹni tó le ni fìlà lai lórí, nítorí Ọlọrun dá Orí fún gbogbo ẹ̀dá alàyè, ṣùgbọ́n ènìà lè̀ lóri, kó má ni fìlà tí ó jẹ́ àtọwọ́dá ọmọ ènìà Nítorí ìdí èyi, Ẹni tó lórí yẹ kó ní Fìlà, nípa lí lo orí lati pèsè àyè àti ohun amáyéderùn Fún àpẹrẹ, ai lo orí lati pèse ohun améyédẹrùn ló fa sún kẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ̀ ni ìlú Èkó nítorí bi Èkó bá lo ọkọ ojú omi, ọkọ̀ Ojúirin pẹ̀lú ọkọ̀ Orí ilẹ̀ lati kó ènìà àti ẹru lati ibìkan dé ibìkejì, sún kẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ̀ á dín kù gidigidi àti wípé a dín ìyà àti àsìkò ti àwọn èrò nlo lójú ọ̀nà lójojúmọ́ kù Ẹfi ojú sọ́na lọ́sọ̀sẹ̀ fún kíkọ nípa àwọn nkan wọnyi lédè Yorùbá àti ìtum̀ọ lédè Gẹ̀ẹ́sì Ìmúlò Òwe, Kíkọ Èdè, Ìtàn àti Ìròyìn tí a lè fi kọ́gbọ́n, Ẹgbẹ́ àti Oúnjẹ Yorùbá ni ìlú London, New York, Chicago, Orlando àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ẹ bá wa sowọ́pọ̀ láti ri pé èdè wa kò kú nípa kíkọ àti kíkà èdè Yorùbá lórí ẹ̀rọ ayélujára Ẹ ṣé púpọ̀, ilé àti èdè Yorùbà kò ní parun o lágbára Èdùmàrè. Àṣẹ Òwe Yorù̀bá ni Ire kì í dé ká má gbọ́ ohun gudugudu, igbe ayọ̀ ti o ti jáde ni gbogbo àgbáyé kọjá gudugudu lati àná Àwọn Ológun ti yin ọ̀kànlélógún sókè lati ki ọmọ titun káàbọ̀ si ayé A kí bàbá àti ìyá ọmọ àti gbogbo ẹbí pé wọ́n kú orí-ire Orúkọ ẹ̀yà ara ṣe pàtàkì lati mọ nípa kíkọ́ èdè nítorí ó ma nwà nínú ọ̀rọ̀ Mí mọ awọn orúkọ wọnyi á́ tún jẹ ki èdè Yorùbá yé àwọn ti ó ni ìfẹ́ lati kọ èdè A lérò wípé àwòrán àti pípè tí ó wà ni abala àwọn ojú ìwé wọnyi yio wúlò Ọ̀mùtí gbàgbé ìṣẹ́ fún ìgbaì diẹ ni, nítorí bí ọ̀mùtí bá jí tán, ìṣẹ́ rẹ kò tán Bí Ìjọba, ẹbí àti ará ti ṣe ìkìlọ̀ tó nípa ọtí àmunpara, bi o ti ngba etí ọ̀tun wọlé lo ngba ti òsì jade fún àwọn ti ọ̀tí ba ti wọ lẹ́wù̀ Ìrònú pẹ̀lú nkan ti ó nfa ọtí àmun jù ṣùgbọ́n ọ̀tí kò lè pa ìrònú rẹ àfi ki ó dá kun, nítorí bi ọtí bá dá lójú ọ̀mùtí, ìrònú á padà Ohun gbogbo níwọ̀ntúnwọ̀nsìn, ọtí àmunpara kò yẹ ọmọ ènìà Ẹ bá wa gbé ọ̀rọ̀ yi yẹ̀wò Àwọn Ilé Ìdájọ́ Àgbà ni ìlú Amerika ṣe ìdájọ wípé ìgbéyàwó ko di dandan kó jẹ́ laarin ọkùnrin àti obinrin Bi wọn ti s'alaiye oro na si, wọn ni kò dára ki àwọn Aṣòfin ti a mọ si Congress, sọ wípé ìgbéyàwó lati jẹ́ laarin ọkùnrin àti obìnrin ni kan ṣoṣo Àkíyèsí ti wọn ṣe ni wípé, ìdí ti àwọn Aṣòfin ṣe sọ bẹ́ẹ̀, ni pé wọn o fẹ́ràn àwọn ti o nṣe ìgbéyàwó ọkùnrin si ọkùnrin tabi obìnrin si obìnrin Ẹ jẹ́ ki a yẹ ọ̀rọ̀ yi wo bó yá a fẹ́ràn ẹ, tàbi a o fẹ́ràn ẹ, ṣe àṣà àdáyébá Yorùbá kankan wa, bi òwe tàbí nkan bẹ́ẹ̀, ti ó sọ ìdí ti a ṣe n fun àwọn ti ó bá ṣe ìgbéyàwó ni ọpọlọpọ ẹ̀tọ́ ti a n fun wọn Ẹ jọ̀wọ́, ẹyin ará Yorùbá blog, ẹ bá wa da si Ẹ sọ ìdí ti aṣe n fun àwọn ti ó bá ṣe ìgbéyàwó ni oriṣiriṣi ẹ̀tọ́, ẹ̀bùn lọ́jọ́, ìgbéyàwó àti àyẹ́sí fún àwọn tó bá wà ni ilé ọkọ Ìdájọ́ yi ṣe pàtàkì, bi o ti ẹ jẹ wípé Amerika lo yi òfin padà pe ìgbéyàwó ki ṣe laarin ọkùnrin àti obìnrin mọ́ lọ́jọ́ òní, ni ọjọ́ kan, Yorùbá, orílẹ̀ èdè Nàíjíríà àti gbogbo ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú yio ṣe ipinu ọ̀rọ̀ yi Àìní ìtẹ́lọ́rùn ló bí gbogbo ìwà burúkú bi irọ́ pípa, olè jíjà, àgbèrè, ojúkòkòrò àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú̀ ilẹ̀ Nàíjíríà á fi ọ̀nà ẹ̀rú wá ipò nítorí àti kó owó ìlú jẹ, wọn ki wúlò fún ìlú ṣùgbọ́n fún ara wọn Il̀ú á dára si ti àwọn ènia bá lè mú òwe Yorùbá tí ó wípé Ìtẹ́lọ́rùn ni Baba Ìwà yí lò lẹhin ọdún mẹrindinlọgbọn wa rí fún ìṣekúṣe si àwọn obìnrin kékèké fún ogún ọdún ó lé Ìwà burúkú kò mọ àgbà tàbí àwọ̀, nítorí náà, o yẹ́ ka kíyèsára pàtàkì àwọn òbí Yorùbá ni wọ́n mú olè lẹkan ó ni òhun ò wá rí, tani fi ọ̀nà han olè Nígbàtí wọn kọ́kọ́ fi ẹ̀sùn ẹṣẹ yi kan Stuart Hall, ó ni kò si nkan tó jọ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àtilẹhin ò̀fin fún àwọn ọmọ obìnrin mẹtala yi pé kò si ẹni tó kọjá òfin, ó jẹ́wọ́ ni ilé-ẹjọ́ Ajá àwọn obìnrin mẹtala yi lẹ́ni lẹhin nítorí lai si Ìjọba, Ọlọpa àti àwọn Amòfin lẹhin wọn, kò si bi wọ́n ti lè dojú kọ Stuart Hall fún ẹ̀ṣẹ̀ ti o ti kọjá fún ọdún mẹrindinlọgbọn sẹhin Ajá wọn ti pa ọ̀bọ, nítorí Adájọ ti sọ Stuart Hall si ẹ̀wọ̀n oṣù mẹdogún Ni abúlé Yorùbá nígbàtí ko ti si ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-mágbèsì tabi ẹ̀rọ amú-òhùn-máwòrán àti ẹ̀rọ ayélujára, àwọn ọmọdé má nkó ara jọ lati ṣe eré lẹhin iṣẹ́ oojọ Bàbá àti Ìyá wọn pàtàkì, ni igba ọ̀gbẹlẹ̀ nígbàtí iṣẹ́ oko din kù Àwọn ọmọdé kunrin mẹta bẹ̀rẹ̀ si ṣe eré ìdárayá leti òkun lai bikità ohun ti ó nlọ ni àyíká Ọmọ kini lérí pé ohun lè gun igi ọ̀pẹ pẹ̀lu ọwọ́ lásá̀n, ekeji ni ohun lè wẹ òkun yi já, ẹni kẹta ni ohun lè ta ọfà si ọ̀run Àjàpá gbọ́ gbogbo ìlérí àwọn mẹta yi ṣe, ó gbé ìròyìn lọ fún Ọba, pé ohun ti ri àwọn ti ó lè ṣe nkan ti ẹni kan kò ṣerí Ọba àti àgbà ìlú kò fẹ́ gba ohun ti Àjàpá wi gbọ́ nítorí ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n o ni ki Ọba ṣe ohun ti ó bá fẹ́ fún ohun ti ìròyìn ti ohun mú wá kò bá ṣẹ Ọba ránṣẹ́ pé àwọn ọmọdé kunrin mẹta yi, pé ki wọn wa ṣe ohun ti wọn ṣèlérí pé wọn lè ṣe Yorùbá ni Ẹnu àìmẹ́nu, ètè àìmétè, ló́ nmú ọ̀ràn bá ẹ̀rẹ̀kẹ́ Ìbẹ̀rù ba àwọn ọmọ yi, ẹbí wọn bẹ Ọba pe eré ọmọdé lásán ni àwọn ọmọ yi fi sọ gbogbo ohun ti wọn sọ, ṣùgbọ́n ẹ̀pa ò bóró mọ́ gbogbo ará ìlú ti pé jọ lati wòran Àwọn ọmọde mẹta yi bẹ̀rẹ̀ si kọ orin arò bayi Èyi ti ó ni ohun lè gun ọ̀pẹ, dé ìdí ọ̀pẹ pẹ̀lú ẹkún Ariwo sọ, inú ará ìlú dùn Nígbàtí ọmọdé keji ti o ni ohun lè wẹ́ òkun ja, gbọ́ ariwo ìdùn nú yi, eleyi ki láyà Bi ti ẹni àkọ́kọ́, ọmọdé keji ti ó ni ohun lè wẹ òkun já, o wẹ dé odi keji, nibiti wọn ti fi ijó àti ayọ̀ pàdé rẹ Eleyi ló fún ọmọdé kẹta ni ìgboiyà pe ohun na lè ṣe ohun ti ohun ti ṣe ìlérí rẹ Ni igbà kẹta ọfà na lọ sókè ọ̀run lai padà Ariwo sọ, ṣùgbọ́n ìtìjú bo Àjàpá Ìwà àti ìṣe ọ̀dọ́ ìgbàlódé, kò fi àṣà àti èdè Yorùbá hàn rárá Aṣọ àlòkù ti gbòde, dipò aṣọ ìbílẹ̀ Ọpọlọpọ aṣọ àgbàwọ̀ yi kò wà fún ara àti lilò ni ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú Ọ̀dọ́ miran a wọ asọ àti bàtà òtútù ninu ooru Ọ̀pọ̀ Olùṣọ́-àgùntàn àti Oníhìnrere, ki wọ́ aṣọ ìbílẹ̀, wọn a di bi ìrẹ̀ pẹ̀lú aṣọ òtútù Èdè ẹnu wọn kò jọ òyìnbó, kò jọ Yorùbá nítorí àti fi ipá sọ èdè Gẹẹsi Òwe Yorùbá ti ó ni Ṣòkòtò àgbàwọ̀, bi kò ṣoni lẹsẹ á fúnni nítan Bi a bá wo òwe yi, àti tun ṣòkòtò àgbàwọ̀ ṣe lati báni mu, ni ìnáwó púpọ̀ tàbi ki ó má yẹni Bi a bá fi òwe yi ṣe akiyesi, aṣọ àlòkù ti wọn kó wọ̀ ìlú npa ọrọ̀ ilẹ̀ wa Àwọn ti ó rán-aṣọ àti àwọn ti ó hun aṣọ ìbílẹ̀, ko ri iṣẹ́ ṣe tó nítorí aṣọ àlòkù ti àwọn ọdọ kó owó lé A lè fi òwe yi bá àwọn ti ó nwọ aṣọ-alaṣọ àti àwọn ti ó fẹ́ gbàgbé èdè wọn nítorí èdè Gẹẹsi wi Òwe yi tún bá àwọn Òṣèlú ti ó nlo àṣà Òṣè́lú ti òkè-òkun lai wo bi wọn ti lè tunṣe lati bá ìlú wọn mu Atunse aṣọ àlòku ju àti rán aṣọ ni titun lọ Ki Òṣèlú bá àwọn ará ìlú jíròrò lati ṣe òfin àti àṣà àti dari ìlú, dára ju pé ki á gba àṣà aláṣà lọ Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni Iṣẹ́ ni oogun ìṣẹ́, jẹ́ òtítọ́, bi òṣìṣẹ́ bá ri owó gbà ni àsìkò, tàbi gba ojú owó fún iṣẹ́ ti wọn ṣe Òṣìṣẹ́ ti ó ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò lórí owó kékeré, kò lè bọ́ ninu ìṣẹ́, nítorí, ọlọ́rọ̀ kò ni ìtìjú lati jẹ òógùn Òṣìṣẹ́ Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́, a fi ìtìjú gé ara wọn kúrú nípa àti bèrè ẹ̀tọ́ wọn Òṣìṣẹ́ míràn a ṣe iṣẹ́ ọ̀fẹ́ fún ọlọ́rọ̀ tàbi ki wọn fúnra wọn gé owó ise wọn kúru lati ri ojú rere ọlọ́rọ̀, nípa èyi, wọn á pa owó fún ọlọ́rọ̀ ni ìparí ọdún Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti o ni Ọ̀dájú ló bi owó, ìtìjú ló bi igbèsè ṣe ló lati ba oloro tàbi o ni ilé-iṣẹ́ ti á lo gbobo ọ̀nà lati ma gba Ẹgbẹ́-òṣìṣẹ́ láyè Ọlọ́rọ̀ kò ni ìtìjú lati lo òṣìṣẹ́ fún owó kékeré A lè lo ọ̀rọ̀ yi lati gba Òṣìṣẹ́ ni ìyànjú ki wọn má tara wọn ni ọ̀pọ̀, nípa bi bèrè owó ti ó yẹ fún iṣẹ́ ti wọn ṣe àti pé ki òṣìṣẹ́ gbìyànju lati kọ iṣẹ́ mọ́ iṣẹ́ lati wà ni ipò àti bèrè ojú owó Ọ̀pọ̀ ẹranko ti ó ni ìwo lóri, ma nlo lati fi gbèjà ara wọ́n ti ewu bá dojú kọ wọ́n Ni ìdà , ìwo igbin wà fún lati fura ninú ewu, nítorí náà, bi igbin bá rò pé ewu wa ni àyíká́, igbin àti ìwo rẹ̀, a kó wọ karaun fún àbò Fún ẹranko àti igbin, ìwo ti ó le ẹranko àti ìwo rírọ̀ igbin wà fún iṣẹ́ kan naa, mejeeji wà fún àbò ṣùgbọ́n fún iwúlò ọ̀tọ̀tọ̀ O yẹ ki igbin mọ iwọn ara rẹ̀ lati mọ̀ pé irú ìwo ohun kò wà fún ohun ijà, lai si bẹ́ẹ̀, wọ́n á tẹ igbin pa A lè lo òwe Yorùbá ti ó ni A sọ̀rọ̀ ẹran ti o ni ìwo, ìgbín yọjú yi fún àwọn ẹ̀kọ́ wọnyi a lè fi bá ẹni ti ó bá jọ ara rẹ lójú wi, aimọ iwọn ara ẹni léwu, ọgbọ́n wà ninu mi mọ agbára àti àbùkù ara ẹni, ki á lo ohun ti a ni fún ohun ti ó yẹ – bi a bá lo ìmọ̀ òṣìṣẹ́ fún irú iṣẹ́ ti wọn mọ̀, á din àkókò àti ìnáwó kù, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Fún àpẹrẹ ilé ti ó ni òrùlé, ilẹ̀kùn àti fèrèsé, àdìrò àti àdògán, omi Ki ba jẹ omi ẹ̀rọ, omi òjò tàbí kànga ṣe pàtàkì àti oúnjẹ Ẹ yẹ àwọn orúkọ àti àwòrán àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ti a lè ri ni àyíká ilé ni ojú ewé yi Ni ayé àtijọ́ ẹsẹ̀ ni gbogbo èrò ma nlo lati rin lati ìlú kan si keji nígbàtí ọkọ̀ ìgbà̀lódé kò ti wọpọ Ilé Ọba àti Ìjòyè ni a ti le ri ẹṣin nítorí ẹṣin kò lè rin ninu igbó kìjikìji ti o yi ilẹ̀ Yorùbá ká Ọrọ Yorùbá ayé òde òní ni Ẹsẹ̀ yá ju mọ́tọ̀ ara lo nfàbọ̀ si Ọ̀rọ̀ yi bá àwọn èrò ayé àtijọ́ mu nítorí ìrìn-àjò ti wọn fi ẹsẹ̀ rin fún ọgbọ̀n ọjọ́, ko ju bi wákà̀̀tí mẹ́fà lọ fún ọkọ ilẹ̀ tàbi ogoji ìṣẹ́jú fún ọkọ̀-òfúrufú Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun ìrìnsẹ̀ ayé àtijọ́ àti ayé òde òní ni èdè Yorùbá, ohun àti àwòrán ti ó wà ni ojú ewé yi Gẹgẹ bi Òwe Yorùba,́ Ọmọ ẹni kì í burú títí, ká fi fún ẹkùn pajẹ Òwe yi bá ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú ti ó ṣẹlẹ̀ si Daniel Pelka mu Kò tọ́ ki ìyá Daniel Pelka ti o yẹ ki ó dáàbò bo ọmọ fi ìyà jẹ ọmọ ọdún mẹrin yi dé ojú ikú Ọmọ kékeré yi jẹ̀ ìyà kú lọ́wọ́ ìyá àti ọkọ rẹ Kini ọmọ ọdún mẹrin lè ṣe lati gbèjà ara rẹ lọ́wọ́ òbí burúkú Kòsí ohun ti ọmọdé lè ṣe, ṣugbọn Ìjọba fa obìnrin àti ọkùnrin burúkú yi lọ si Ilé-Ẹjo Wọ́n gba ìdájọ́ èyí ti wọn ni lati lo ọgbọn ọdún ó kéré jù Ẹ wo ìròyìn yi Gẹgẹbi òwe Yorùbá Ẹni ti ó ni ki ará ilé ohun má là, ará ìta ni o ya láṣọ Òwe yi là le fi ba awọn èyaǹ wa wi, nítorí bi Òyìnbó bá bẹ̀rẹ̀ si ṣe irú àjọ̀dún yi, awọn enia wa a tò pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ lati gba àyè lati fi iṣẹ́ ọnà àti àṣà Yorùbá ni irú ibi bẹ́ẹ̀ Bi èrò ìwòran ti ó fẹ́ mọ nípa iṣẹ́ ọ̀na Yorùbá ti pọ̀ tó, kòsí oníṣẹ́ ọnà bi onilù, olórin ìbìlẹ́, oníṣòwò ọjà ìbílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ lati polówó iṣẹ́ ọnà àti àṣà Yorùbá ni àjọ̀dún yi Awọn ẹ̀ka Yorùbá ti ó wà ni Brazil ló kó onílù àti oníjò Batala ti ó dá awọn èrò lára ya Awon olonje Yorùbá ri oja ta Awọn onilù, oníṣòwò ibile, olórin ibile, oniṣẹ ọna ati eléré ìbílẹ̀ Yorùbá ni ìlú-ọba pàdánù àti jẹ ọrọ̀ àti polongo iṣẹ ọwọ́ wọn Ó ṣe pàtàkì lati parapọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ lati gbé àṣà, iṣẹ́ ọnà àti èdè Yorùbá lárugẹ Yorùbá ni Ọmọdé ò jobì, àgbà ò jẹ oye, òwe yi bá àwọn òbí ti ó kọ ọmọ sílẹ̀, ìyá ti ó ta ọmọ, bàbá ti ó sá fi ọmọ sílẹ̀ àti àwọn ti o fi ìyà jẹ ọmọ, irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí bayi ni òṣì má ta pa Kò sí àyè fún ọmọ irú àwọn bayi lati mọ wọn lójú nítorí wọn o si nílé lati ṣe ojuṣe wọn gẹ́gẹ́bí òbi ati lati kọ́ ọmọ aláìgbọràn Irú orin bayi ló tọ́ sí irú òbí bẹ́ẹ̀ Orin yi ni Olùkọ́ ma fi ńkọ́ àwọn ọmọ ilé-ìwé alakọbẹrẹ nigbà ilé-ìwé ọ̀fẹ́ ti àwọn Òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá ti Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ṣe olórí rẹ Ni ayé ìgbà wọnyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí a ma fi ebi panú, ṣiṣẹ́ kárakára tàbí ta ohun ìní lati pèsè fún àwọn ọmọ àti lati rán ọmọ lọ sí ilé-ìwé gíga O yẹ ki ọmọ bọ̀wọ̀ fún irú àwọn òbí wọnyi Ìyàtọ̀ diẹ̀ ló wà láàarín awọn ẹru igbéyàwó ti a kọ́ si ojú iwé yi lati idile si idile Kò si àyè àti sin abo ewúrẹ́ fún awọn ti o ńgbé ìlú nla tàbi ìlú òyìnbó́, nítorí náà a lè fi owó dipò fún ìyá àgbà ni abúlé ki wọn ra abo ewúrẹ́ lati sin fún ìyàwó Awọn ẹlẹ́sìn ìgbàlódé lè sọ wipé awọn ò fẹ́ ki wọn fi ataare àti obì ṣe àdúrà fún ọkọ ati ìyàwó A tún ṣe akiyesi wipé wọn ki tú àpóti ìyàwó mọ, nítorí ni ayé àtijọ́, wọn yio ṣi àpóti ki gbogbo ẹbí ri awọn ohun ẹ̀ṣọ́ ti ọkọ ìyàwó ra fún ìyàwó rẹ, eyi bo à��írí ìnáwó lori awọn ohun ẹṣọ Ẹbi tún lè wo ṣe fún ọkọ ìyàwó lati gba idaji oye iṣu tàbi ẹrù lati bo ni àṣiri Erin jẹ ẹranko ti Ọlọrun da lọ́lá pẹlu titobi rẹ ninu igbo Yorùbá ni Koríko ti Erin bá ti tẹ̀, àtẹ̀gbé ni láyé, oko ti Erin bá wọ̀, olóko bẹ wọ igbèsè tori ibajẹ ti o ma ṣẹlẹ̀ si irú oko bẹ Gbogbo ẹranko bọ̀wọ̀ fún Erin, nítorí Kìnìún ọlọ́là ijù kò lè pa Erin Bi Erin ti tóbi tó, ni ó gọ̀ tó Ni ọjọ́ kan, gbogbo ẹranko pe ìpàdé lati pari ìjà fún Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti Kìnìún Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ni bi ohun ba pa ẹran, Kìnìún a fi ògbójú gba ẹran yi jẹ Kàkà ki Erin da ẹjọ́ pẹ̀lú òye, ṣe ló tún dá kun Ìhàlẹ̀ àti ìgbéraga ni àwùjọ yi bi awọn ẹranko yoku ninu O bi Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ninu to bẹ gẹ ti kò lè fọhùn Àjàpá nikan lo dide lati fún Erin ni èsì ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ẹranko yoku bú si ẹ̀rín nítorí wọn fi ojú di Àjàpá Dipo ki Àjàpá panumọ́, ó pe erin níjà Ni ọjọ́ ìjà, Erin kò múra nítorí ó mọ̀ pé bi Àjàpá ti kéré tó, bi ohun bá gbé ẹsẹ̀ le, ọ̀run lèrọ̀ Àjàpa mọ̀ pé ohun ko ni agbára, nítorí eyi, ó dá ọgbọ́n ti yio fi bá Erin jà lai di èrò ọ̀run Àjàpá ti pèsè, agbè mẹta pẹlu ìgbẹ́, osùn àti ẹfun ti yio dà lé Erin lóri lati dójú ti Ó tọ́jú awọn agbè yi si ori igi nitosi ibi ti wọn ti fẹ́ jà, ó mọ̀ pé pẹ̀lú ibinu erin á jà dé idi ibi ti yio dà le lori Awọn ẹranko péjọ lati wòran ijà láàarín Àjàpá àti Erin Àjàpá mọ̀ pe bi erin bá subú kò lè dide, nígbàtí ti ijà bẹ̀rẹ̀, ẹhin ni Àjàpá wà ti o ti nsọ òkò ọ̀rọ̀ si erin lati dá inú bi Pẹ̀lú ibinú, ki ó tó yípadà dé ibi ti Àjàpá wa, Àjàpá a ti kósi lábẹ́, eleyi dá awọn ẹranko lára yá Yorùbá ni Bi ìyà nla ba gbeni ṣánlẹ̀, kékeré á gorí ẹni ni ikẹhin, Àjàpá bori erin pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ẹranko gbé Àjàpá sókè pẹ̀lú ìdùnnú gun ori ibi ti erin wó si Òwe Yorùbá ti ó ni Bi ará ilé ẹni ba njẹ kòkòrò búburú ti a ò sọ fun, hẹ̀rẹ̀huru rẹ kò ni jẹ ki a sùn bá iṣẹlẹ ọ̀rọ̀ àti pèsè ina monamona yi mu Pẹlu gbogbo owó ti ó ti wọlẹ̀ lóri àti pèsè ina mona-mona, ará ilé ẹni ti o ńjẹ kòkòrò búburú ti jẹ́run Ariwo yi pọ to bẹ gẹ, ti àtisùn di ogun Àti ọ̀sán àti òru ni ariwo ẹ̀rọ-iná kékèké yi ma ńdá sílẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tó burú jù ni herehuru ti òru Ki ṣe omi, epo-rọ̀bi, èédú nikan ni a fi lè ṣe ètò ina mona-mona A lè fi oòrùn, atẹ́gùn àti pàntí ti ó pọ̀ ni orílẹ̀ èdè wa ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ pèsè iná mona Ìlú ti kò ni oòrùn tó ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú ńfi oòrùn pèsè iná mona-mona Ohun ìtìjú ni pé fún bi ọgbọ̀n ọdún ó lé díẹ̀, àwọn Òṣèlú àti ará ìlu, kò ri ará ilé ti ó ńjẹ kòkòrò búburú báwí Yorùbá ka ọmọ si ọlá àti iyì ti yio tọ́jú ìyá àti bàbá lọ́jọ́ alẹ́ Eyi han ni orúkọ ti Yorùbá nsọ ọmọ bi Ọmọlọlá, Ọmọniyì, Ọmọlẹ̀yẹ, Ọmọ́yẹmi, Ọlọ́mọ́là, Ọlọ́mọlólayé, Ọmọdunni, Ọmọwunmi, Ọmọgbemi, Ọmọ́dára àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ A o tun ṣe akiyesi ni àṣà Yorùbá pe bi obinrin ba wọ ilé ọkọ, wọn ki pe ni orúkọ ti ìyá ati bàbá sọ, wọn a fun ni orúkọ ni ilé ọkọ Nígbàtí ó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé wọn a pe ni Ìyàwó ṣùgbọ́n bi ó bá ti bímọ a di Ìyá orúkọ àkọ́bí, bi ó bá bi ibeji tabi ibẹta a di Ìyá Ibeji tàbi Ìyá Ibẹta Bàbá ọmọ a di Bàbá orúkọ ọmọ àkọ̀bí, Bàbá Ibeji tàbi Bàbá Ìbẹta Nítorí idi eyi, ìgbéyàwó ti kò bá si ọmọ ma nfa irònú púpọ̀ Ni abúlé kan ni aye atijọ, ọkọ ati ìyàwó yi kò bímọ fún ọpọlọpọ ọdún lẹhin ìgbéyàwó Nítorí àti bímọ, wọn lọ si ilé Aláwo, wọn lọ si ilé oníṣègùn lati ṣe aajo, ṣùgbọ́n wọn o ri ọmọ bi Aladugbo wọn gbà wọn niyanju ki wọn lọ si ọ̀dọ̀ Olóri-awo ni ìlú keji Ọkọ àti ìyàwó tọ Olóri-awo yi lọ lati wa idi ohun ti wọn lè ṣe lati bímọ Olóri-awo ṣe iwadi lọ́dọ̀ Ifa pẹ̀lú ọ̀pẹ̀lẹ̀ rẹ, o ṣe àlàyé pe ko si ọmọ mọ lọdọ Òrìṣà ṣùgbọ́n nígbàtí ẹ̀bẹ̀ pọ, o ni ọmọ kan lo ku lọdọ Òrìṣà-Omi, ṣùgbọ́n ti ohun bá gba ọmọ yi fún wọn kò ni bá wọn kalẹ́, nítorí ti o ba lọ si odò ki ó tó bi ọmọ ni ilé ọkọ yio kú, Òrìṣà-Omi á gba ọmọ rẹ padà Ààntére lọ fọ abọ́ lódò Ìyàwó lóyún, ó bi obinrin, wọn sọ ni Ààntéré eyi ti ó tumọ si Ọmọ Omi Gbogbo ẹbi àti ará bá wọn yọ̀ ni ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ Ni ọjọ kan, Àànt��ré bẹ awọn òbí rẹ pé ohun fẹ́ sáré lọ fọ abọ́, awọn òbí rẹ kọ Nígbàtí ẹ̀bẹ̀ pọ wọn gbà nítorí o ti dàgbà tó lati wọ ilé-ọkọ, wọn ti gbàgbé ewọ ti Olóri-awo sọ fún wọn pe, o ni lati wọ ile ọkọ ki o to bímọ Ààntéré dé odò, Òrìṣà-omi, ri ọmọ rẹ, o fi iji nla fa Ààntéré wọ inú omi lai padà Ìyá àti Bàbá Ààntéré, reti ki ó padà lati odò ṣùgbọ́n kò dé, wọn ké dé ilé Ọba, Ọba pàṣẹ ki ọmọdé àti àgbà ìlú wa Ààntéré lọ Nigba ti wọn dé idi odò, wọn bẹrẹ si gbọ orin ti Ààntéré nkọ, ṣùgbọ́n wọn ò ri abi-nibi wọn Àwa òbí lati yi ìhà ti a kọ si èdè Yorùbá padá, ti a kò bá fẹ́ ki o pòórá Òwe Yorùbá kan tilẹ sọ wípé, Onígbá Io npe igbá rẹ ni pankara, ti a fi nbaa fi kolẹ Gẹ́gẹ́ bi òbí, ohun ti a bá fi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wa lati ìgbà èwe ni wọn yio gbọ́njú mọ, ti wọn yio si dìmú Ṣugbọn kini a nfi lélẹ̀ Ẹ̀kọ́ Àjòjì, Eyi yi ni Èdè Gẹẹsi Àwa òbí papa, ti a rò pé a ti lajú ju pé kaa máà fi èdè abínibí wa maa ba àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ nílé lọ Àti kàwé, a si ti bọ́ si ipele tó ga ju èyi ti a bi wa si lọ, nítorí na, èdè wa di ohun ìtìjú àti àbùkù, ti kò yẹ ipò ti a wà Ẹ jẹ́ ki a kọ́ ọgbọ́n lára àwọn Ìgbò, Hausa, òyìnbó, China àti India,ki a si fi won ṣe àwòkọ́ṣe Kò si ibi ti àwọn wọnyi wà, yálà nílé tabi lóko, èdè wọn, ni wọn maa ba awọn ọmọ sọ Àwọn òyìnbó gbé èdè wọn ni arugẹ, ni ó mú ki idaji gbogbo enia ni àgbáyé ki ó maa lo èdè wọn Àwọn ará ìlú China, ẹ̀wẹ̀, kò fi èdè wọn ṣeré rárá, tó bẹ́ẹ̀ ti odindi ìlú America, àti àwọn kan ni ilẹ̀ adúláwọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ si kọ awọn ọmọ ilé-ìwé wọn ni Mandarin, ẹ̀yà èdè China Ti a kò bá fẹ́ ki èdè Yorùbá ki ó di ohun ìgbàgbé, a ni lati yi padà, ki á si ṣe àtúnṣe Ẹ jẹ́ ki ó jẹ́ èdè yi ni àwọn ọmọ wa yio kọ́ gbọ́, ti á o si má ba wọn sọ ninu ilé, dípò èdè Gẹẹsi Yorùbá ni Omi lènìyàn, bi ó bá ṣàn siwájú á tún ṣàn sẹ́hìn Òwe yi túmọ̀ si wipé lati ọjọ́ ti aláyé ti dáyé ni èniyàn ti nkúrò ni ìlú kan lọ si ikeji fún ọpọlọpọ idi Èniyàn ma nkúrò ni ìlú abínibí nítorí ogun, ìyàn, ọ̀gbẹlẹ̀, ọrọ̀ ajé, ìtẹ́síwájú ninu ẹ̀kọ́, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú kún fún wàrà àti oyin nítorí ọgọrun-din-marun ohun àlùmọ́nì gbogbo àgbáyé wà ni orílẹ̀ èdè naa Lára ìwà burúkú yi ló ndá ogun àti ọ̀tẹ̀ si ìlú àti tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun awọn ọ̀dọ́ Èrè awọn ìwà ìbàjẹ́ wọnyi ti ba ìlú jẹ, èyi jẹ ikan ninu ohun ti ó dá kún ohun ti ọ̀dọ́ ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú fi nkúrò lọ si òkè-òkun ni ọ̀nà kọnà Iroyin awọn ọdọ òṣìṣẹ́ ti o nṣi kúrò ni ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú ti ọkọ̀ wọn dà si òkun ni ìlú Lampedusa, Italy kàn loni ọjọ́ Ẹti, osu kewa, ọjọ́ kẹrin ọdún Ẹgbàálemẹ̀talá Iroyin ikú ọ̀rùndínrínwó òṣìṣẹ́ tó ṣègbé si òkun kan Yorùbá ni Ẹ̀bẹ̀ là mbẹ̀ òṣìkà ki ó tú ìlú rẹ̀ ṣe Òwe yi bá awọn Oṣelu ti a npe ni Alágbádá àti awọn Olórí ìjọ ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, ki wọn jọwọ tún ìlú wọn ṣe Ọpọlọpọ ewu ti awọn ọdọ nla kọjá iba din kù bi awọn Olórí ìlú bá lè fi ìwà burúkú sílẹ̀, ki wọn tu ìlú ṣe nípa ṣi ṣe ìdájọ́ fún Olórí ti ó bá ṣe iṣẹ́ ibi bi ki kó owó ìlú jẹ àti awọn ìwà ìbàjẹ́ yoku Ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ikan ninu ẹ̀yà nlá lára orílẹ̀ èdè Nàíjíríà Orílẹ̀ èdè yi gba ominira lati ọ̀dọ̀ ilú-ọba ni ọdún mẹ́tàléladọta sẹhin Lati igba ti Nàíjíríà ti gba ominira, Kàkà ki ewé àgbọn dẹ̀, koko ló tún nle si Bi ọdún ti ńgorí ọdún ni ó nle koko si fún ará ilú Olórí ilú ti a npe ni Ìjọba mba ọrọ̀ ilú jẹ pẹ̀lú iwà ibàjẹ́ bi gbigba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, ojúkòkòrò, rírú òfin ti wọn fúnra wọn fi silẹ̀, fifi èrú gba Ìjọba, kíkó ọrọ̀ ilú lọ si òkè-òkun àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Kò si ìyàtọ̀ laarin Ìjọba Ológun àti Òṣèlú Èrè iwà burúkú lati ọ̀dọ̀ Òṣèlú ti ran awọn ará ilu Oriṣiriṣi iwà burúkú ti kò ṣẹlẹ̀ láyé àtijọ́ ti bẹ̀rẹ̀ si ṣẹlẹ̀ Fún àpẹrẹ, gbọmọgbọmọ ti gbòde, olè jíjà, jìbìtì, tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun, ọ̀tẹ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Kò si iná, omi, ilé-ìwé fún ọmọ aláìní, ojú ọ̀nà ti bàjẹ́, awọn ará ilú njẹ ìyà, ọpọlọpọ ọdọ jade ilé-ìwé wọn ò ri iṣẹ́, èyi to ri iṣẹ́ ngba owó ti kò tó jẹun àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Bi Nàíjíríà ti nṣe àjọ̀dún kẹtaleladọta ni ọjọ́ kini oṣù kẹwa, ó yẹ ká gbé òwe Yorùbá ti ó ni Ọmọ to yi ko gbọn, Ìyá ni ko ma ṣa kú, kilo npa ọmọ bi agọ̀, yẹ̀wò Ìlú tó bá gbọ́n ni lati kó ara pọ̀ lati ṣe àpérò fún àtúnṣe nkan ti ó ti bàjẹ́, ki agọ̀ ma bà pa orílẹ̀ èdè Bi ó ti wù ki ó ri, ẹni ọdún bá láyé, ó yẹ ki ó dúpẹ́, ki ó ni ireti pé ọ̀la yi o dára, nítorí eyi, ẹ̀yin olólùfẹ́ èdè àti àṣà Yorùbá, ẹ kú ọdún ominira o Òwe Yorùbá yi ṣe gba àwọn ti o nbẹ̀rù nigba gbogbo níyànjú wípé ó yẹ ki èniyàn fara balẹ̀ lati ṣe iwadi ohun ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀ ki ó tó kú sílẹ̀ de ikú Ẹlòmíràn, kò ni ṣe iwadi ohun ti àwọn èniyàn fi ńsáré, ki ó tó bẹ̀rẹ̀ si sáré Ọpọlọpọ ti sa wọ inú ewu ti wọn rò wípé àwọn sá fún Fún àpẹrẹ, nígbàtí iná ajónirun balẹ̀ ni àgọ́ Ológun ni Ikẹja ni ìlú Èkó ni bi ọdún mẹjọ sẹhin Bi àwọn kan ti gbọ́ ìró iná ajónirun yi, wọn sáré titi ọpọ fi parun si inú irà ni Ejigbo ni ọ̀nà jínjìn si ibi ti ìṣẹ̀lẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ Àpẹrẹ miran ti a lè fi ṣe àlàyé pé Ọ̀run ńyabọ̀, ki ṣé ọ̀rọ̀ ẹnìkan ni ẹni ti ó sọ pé ohun ri wípé ayé ti fẹ parẹ́, àwọn kan gbàgbọ́, wọn bẹ̀rẹ̀ si ta ohun ìní wọn Àti ẹni ti ó ta ohun ìní àti ẹni ti ó ra, kò si ninú wọn ti ó ma mú nkankan lọ ti ayé bá parẹ nitotọ Èkó jẹ́ olú ìlú Nàíjíríà fún ọpọlọpọ ọdún, ki wọn tó sọ Abuja di olú ìlú Nàíjíríà, ṣùgbọ́n Èkó ṣi jẹ́ olú ìlú fún iṣẹ ọrọ̀ gbogbo Nàíjíríà Nítorí eyi, gbogbo ẹ̀yà Nàíjíríà àti àwọn ará ìlú miran titi dé òkè-òkun ló wà ni Èkó Yorùbá ni èdè ti wọn nsọ ni ìgboro Èkó, ṣùgbọ́n ọpọlọpọ gbọ èdè Gẹẹsi, pàtàkì àwọn ti ki ṣé ọmọ Yorùbá Ẹ wo díẹ̀ ni àwọn ìṣe àti ọ̀rọ̀ ni ìgboro Èkó Gẹgẹbi àpè júwe, ẹranko a fàyà fà jẹ ẹranko ti ó ni àwọ̀, omiran ni oro, omiran ni ikarawun, wọn si ńyé ẹyin Fún àpẹrẹ irú àwọn ẹran wọnyi ni Ejò, Àjàpá, Alangba àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ẹ wo àwòrán àti pipe irú àwọn ẹranko wọnyi ni ojú ewé yi Ni asiko ọdún, pàtàkì, asiko ọdún iranti ọjọ ibi Jésù, bi oúnjẹ ti pọ̀ tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti o wa ni Òkè-okun àti àwọn díẹ̀ ni ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, bẹ́ẹ̀ ni o ṣọ̀wọ́n tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àgbáyé Ò̀we Yorùbá ni, Ọ̀kánjúwà-á bu òkèlè, ojú rẹ à lami Bi enia ò bá ni ọ̀kánjúwà, á mọ irú òkèlè ti ó lè gba ọ̀nà ọ̀fun rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀kánjúwa á bu lai ronu pe òkèlè ti ó ju ọ̀nà ọ̀fun lọ á fa ẹkún Òwe yi bá àwọn ti ó ṣe jura wọn lọ tàbi ki ó jẹ igbèsè lati ra ẹ̀bùn, oúnjẹ ti wọn ò ni jẹ tán, aṣọ, bàtà àti oriṣiriṣi ti wọn ri ni ìpolówó lai mọ̀ pé ọdún á ré kọjá Lẹhin ọdún, ọ̀pọ̀ a fi igbèsè bẹ̀rẹ̀ ọdún titun, eyi a fa ìrora àti ọ̀rọ̀ ti ó ṣòro si ayé irú ẹni bẹ́ẹ̀ Yorùbá ni Ájẹ ìwẹ̀hìn ló ba Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ, nítorí eyi ìkìlọ̀ fún ẹ̀yin ti ẹ ni ìfẹ́ àti gbé èdè àti àṣà̀̀ Yorùbá lárugẹ, pe ki ẹ ṣe ohun gbogbo ni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Ẹ kú ọdún o, ọdún titun ti o ḿbọ̀ lọ́nà á ya abo fún gbogbo wa Lati ọjọ́ ti aláyé ti dá ayé ni Yorùbá ti ni ìgbàgbọ́ ninu ki a gba àdúrà nítorí pe ohun gbogbo fẹ́ àdúrà Ohun ti o dára fẹ́ àdúrà ki ó bà lé dára si, eyi ti kò dára na fẹ́ àdúrà ki ó bà lé yanjú Bi àwọn Ìgbàgbọ́ tàbi ilé-àdúrà aláṣọ funfun ti ńlo Àbẹ́là gba àdúrà a ni Yorùbá ma ńlo àwọn ohun ọ̀gbin bi Orógbó, Obì, Atare àti Oyin nibi ètò ìgbéyàwó, ìsọmọ lórúkọ, ìṣílé, àjọ̀dún àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ẹ jẹ ki a ṣe akiyesi bi Yorùbá ti ńlo wọn fún àdúrà Ọpọlọpọ ìgbà ni a ki mọ ẹni ti o gbin igi orógbó nítorí igi rẹ lè pé igba ọdún, nítorí eyi, Yorùbá ma ńlo lati gbàdúrà nibi ṣiṣe fún ẹmi gigun pe wa gbó wa tọ́ Obì wulo fún ọrọ ajé Yorùbá ni ọdọdún la nri orógbó, ọdọdún la nri obì lori atẹ nítorí eyi wọn a lo fún àdúrà pe obì a bi iku, àti pé ẹni na a ṣe àmọ́dún Ọmọ pọ ninu atare, nítorí eyi wọn a fi gba àdúrà, pàtàkì fún ẹni ti o nṣe ìgbéyàwó pe ilé wọn á kún fún ọmọ tàbi nibi ìsọmọ lórúkọ pe bi wọn ṣe bi ọmọ na, ilé tirẹ̀ na á kún fún ọmọ Òwe Yorùbá ni Dídùn là ḿbá láfárá oyin, nítorí eyi wọn a lo oyin lati gba àdúrà nibi ìgbéyàwó, ìsọmọ lórúkọ àti ṣiṣe yoku pe ayé ẹni ti o nṣe nkan á dùn bi oyin Òwe Yorùbá ti o ni Ká tó ri erin ó digbó, ká tó ri Ẹfọ̀n ó dọ̀dàn, ká tó ri ẹyẹ bi Ọ̀kin ó di gbére fihan pé ki ṣe ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú nikan ni irú Nelson Mandela ti ṣe ọ̀wọ́n, ṣugbọn gbogbo àgbáyé Melo ninu Olori Òṣèlú àti àwọn Òṣèlú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú ló lè ṣe bi Nelson Mandela Bi wọn dé ipò giga wọn ki fẹ kúrò, wọn a paniyan, wọn a jalè, wọn a ta enia wọn àti oriṣiriṣi iwa burúkú miran lati di ipò na mu Nelson Mandela ṣe ẹ̀wọ̀n fún ọdún mẹta-din-lọgbọn nítorí ó̀ gbìyànjú lati tú àwọn enia rẹ sílẹ̀ ni oko ẹrú O di enia dúdú àkọ́kọ́ lati dé ipò Olori Òṣèlú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú Kò lo ipò yi lati gbẹ̀san iṣẹ́ ibi ti àwọn aláwọ̀ funfun ṣe si tàbi ijiya rẹ ni ẹ̀wọ̀n Ó fi apẹrẹ onígbàgbọ́ rere han nítorí ó dariji àwọn ti ó fi ìyà jẹ́ ohun àti àwọn enia rẹ tori ki ilú rẹ lè tòrò Ẹyẹ bi ọ̀kín ṣọ̀wọ́n, kò du lati kú si ori ipò, lẹhin ọdún marun ó gbé ipò sílẹ̀ ki ẹlòmíràn lè bọ́ si Ọmọ ọdún marun-din-lọgọrun ni ki ó tó pa ipò dà, bi o ti ẹ̀ jẹ́ pé Nelson Mandele ti di arúgbó, gbogbo àgbáyé ò fẹ́ ki ó kú, nítorí ẹyẹ bi ọ̀kín rẹ ṣọ̀wọ́n Bi àwọn Òṣèlú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú yoku ba le kọ́gbọ́n lára ìgbà àti ikú Nelson Mandela, ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú á dára Gbogbo àgbáyé ṣè dárò Madiba Nelson Mandela Gbogbo ọmọ Yorùbá ni ó dìgbà, ó dìgbóṣe, ó dàrìnàkò, ó dojú àlá ká tó tún ríra O bi ọmọ mẹta ti wọn jọ ngbe nítorí ìyàwó rẹ ti kú Bi Bàbá yi bá fẹ́ la ija yio sọ pé ẹ má jà, a ò mọ ohun ti Ọlọrun fi ohun ti ẹ ńjà lé lori ṣe, nítorí náà bi eyi o ṣe, omiran yio ṣe Ni ọjọ́ kan, ọmọ kú fún obinrin olùbágbélé Bàbá Beyioṣe Bàbá tún dé ọdọ obinrin yi lati tu ninu, o sọ fún pe Bi eyi o ṣe, omiran yio ṣe – ẹ pẹ̀lẹ́, a o mọ̀ ohun ti Ọlọrun fi ṣe Ọrọ ìtùnú yi bi ẹniti o ṣe ọ̀fọ̀ ọmọ ti ó kú ninu tó bẹ gẹ ti o fi gbèrò pe ohun yio dán ìgbàgbọ́ Bàbá Beyioṣe wo nípa wiwo ohun ti yio ṣe ti ọmọ ti rẹ náà bá kú Ni òwúrọ̀ ọjọ́ kan, Bàbá Beyioṣe, sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé ohun fẹ ji dé ibikan Ó ṣe ètò pé ki wọn mu ògì àti àkàrà ni òwúrọ̀ ọjọ́ na Àwọn ọmọ ji, wọn lọ si àrò, wọn po ògì lai mọ pe, obinrin ti ọmọ rẹ ku ti bu májèlé si ògì yi Àwọn ọmọ gbé ògì wọlé ṣùgbọ́n wọn dúró de ikan ninu wọn ti ó lọ ra àkàrà Nígbàtí ẹni ti ó lọ ra àkàrà de, ẹ̀gbọ́n àgbà pin àkàrà ṣùgbọ́n ija bẹ silẹ nítorí ẹni ti o pin àkàrà ko pin daradara Nibi ti wọn ti ńja, ògì ti o jẹ ounjẹ àárọ̀ àwọn ọmọ Bàbá Beyioṣe dànù Ori igbe ògì ti ó dànù ni àwọn ọmọ wa nígbàtí Bàbá Beyioṣe wọlé Gẹ́gẹ́ bi iṣe rẹ, ó sọ fún àwọn ọmọ pé ẹ má jà, bi eyi o ṣe, omiran yio ṣe – a o mọ ohun ti Ọlọrun fi ṣe Obinrin ti o fi májèlé si ògì, ti o reti ki àwọn ọmọ Bàbá Beyioṣe ó kú, ba jade nígbàtí ó gbọ́ ohun ti o sọ lati tu àwọn ọmọ rẹ ninu Ó jẹ́wọ́ pe nitotọ, onígbàgbọ́ ni Bàbá Beyioṣe nítorí ohun ti ohun ṣe, ó wá tọrọ idariji Bàbá Beyioṣe dariji, ó fún àwọn ọmọ lówó lati ra ounjẹ miran Ọ̀gá ninu Olórin Fẹlá Anikulapo-Kuti kọrin pé Ọjọ́ wo la ma bọ o, lóko ẹrú, orin yi fa ìbèrè wípé ọjọ́ wo la ma bọ ninu òkùnkùn ni orílẹ̀ èdè Nàíjíríà Bi eré bi àwàdà, dákú-dájí iná mọ̀nà-mọ́ná bẹrẹ ni àsikò Ìjọba Sagari, ni bi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n sẹhin Ni àsikò yi, ki ṣe pe iná ti ilú pèsè kò tó, ṣùgbọ́n a ṣe akiyesi pé awọn òṣìṣẹ́ ni àsikò na lọ ńyọ nkan lára àpóti iná, nítorí eyi, ki ṣe gbogbo àdúgbò ni ki ni iná Fún akiyesi, iná ilé-iwé giga àti agbègbè rẹ, awọn ilé iṣẹ́ bi ìlèṣẹ ọkọ̀ òfúrufú, ilé ìwòsàn àti bẹbẹ lọ ki lọ Bi eniyan ba yọ́ ilẹ̀ dà, ohun burúkú a ma yọ́ni ṣe, nígbàtí awọn òṣìṣẹ́ oníṣẹ́ ibi kò ri ẹni ba wọn wi, ọ̀rọ̀ iná lilọ bẹrẹ si gbòrò si Pẹlu gbogbo owó ti wọn ti na lati tú ọ̀rọ̀ iná mọ̀nà-mọ́ná ṣe, ó burú si lai ya ilé-iṣẹ́ àti ibi kankan sílẹ̀ ninu òkùnkùn Yorùbá ni ohun tó yẹ ni, lo yẹ ni, òkùnkùn o yẹ ọmọ eniyan, nítorí òkùnkùn ti ilé-iṣẹ́ mọ̀nà-mọ́ná fa fún ará ilú, ọpọlọpọ ilé-iṣẹ́ ti kò kúrò ni Nàíjíríà eleyi din ìpèsè iṣẹ́ kù, kò si iná lati tọ́jú ounjẹ eleyi jẹ ki ounjẹ wọn si, ìnáwó lori ẹ̀rọ iná mọ̀nà-mọ́ná pẹ̀lú ariwo ki jẹ ki eniyan sùn bẹni kò jẹ́ ki eniyan tabi ilé-iṣẹ́ fi owó pamọ́ Á lérò wípé awọn ilé-iṣẹ́ ti wọn pin iná pi pèsè fún a yọ ilú kúrò ninu òkùnkùn nítorí òkùnkùn kò yẹ ọmọ eniyan Gbogbo olólùfẹ́ èdè Yorùbá, pàtàkì àwọn ti o fi ìfẹ́ tẹ̀ lé àkọ-sílẹ̀ ọ̀rọ̀ gbígbé èdè àti àṣà Yorùbá́ lárugẹ lóri ẹ̀rọ ayélujára, mo jẹ yin ni àlàyé ohun ti ojú ri lẹhin àbọ̀ oko Ẹ o ṣe akiyesi wípé, ìwé kikọ wa din kù diẹ nítorí adarí ìwé lọ bẹ ilé wò fún ìgbà diẹ Ni gbogbo àsìkò ti adarí ìwé fi wa ni ilé ìṣòro nla ni lati lè kọ ìwé lori ayélujára nítorí dákú-dájí iná mọ̀nà-mọ́ná Lẹhin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, kàkà ki ewé àgbọn dẹ, koko ló tún nle si A ṣe akiyesi pé nkan wọ́n ni ilé ju oko lọ, pàtàkì ìnáwó lórí ounjẹ, ẹrọ iná mọ̀nà-mọ́ná àti ọkọ̀ wíwọ̀ Ai si iná, ariwo ẹ̀rọ iná mọ̀nà-mọ́ná, fèrè ọkọ̀ àti sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ kò jẹ́ ki akọ̀we yi gbádùn ilé bi oko A lè sọ wípé àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ngbiyanju, ṣùgbọ́n omi pọ̀ ju ọkà lọ Àyè iṣẹ́ ti ó yẹ ki Ìjọba àpapọ̀ ṣe ti wọn kò ṣe ńfa ìnira fún ará ìlú Ẹ̀bẹ̀ là ńbẹ òṣìkà ki ó tú ìlú rẹ̀ ṣe, nítorí eyi, a bẹ Ìjọba àti àwọn Gómìnà pé ki wọn sowọ́ pọ̀ lati tú orílẹ̀ èdè ṣe ni pàtàkì ìpèsè ohun amáyé-dẹrùn Ìròyìn ti ó nlọ lọ́wọ́ ni orílẹ̀ èdè Nàíjíríà ni pé Aṣojú-ọba nkó ọrọ̀ ilú dànù gẹgẹ bi iṣe awọn yoku lati ra ọkọ̀̀ ojú-ogun Bi a bá wo iṣe àti àṣà Yorùbá, a o ri pe àwọn Àlejò lati Òkè-Òkun ti o ni Inú Yorùbá ló dùn jù ni àgbáyé kò jẹ̀bi Kò si ibi ti enia lè dé ni olú-ilú àti ìgbèríko Yorùbá ti kò ni ri ibi ti wọn ti ńṣe àpèjẹ Yorùbá ni Ọjọ́ gbogbo bi ọdún, pàtàkì ni ilú Èkó, lati Ọjọ́-bọ̀ titi dé Ọjọ́-Àìkú ni wọn ti ńṣe àpèjẹ, ilú miran ńṣe àpèjẹ ni Ọjọ́-Ajé fún àpẹrẹ – Ikẹrẹ-Ekiti Ọpọlọpọ ayẹyẹ àti Ìjọ́sìn ló mú ìlù, orin, ijó àti àsè dáni Ni gbogbo ilẹ̀ Yorùbá, àti Ọlọ́rọ̀ àti Òtòṣì ló ńṣe àpèjẹ kan tàbi keji Bi wọn ò kómọ-jade, wọn a ṣe ìsìnkú tàbi yi ẹ̀hìn òkú padà, ìṣílé, ọjọ́-ibi, igbéyàwó, Ìwúyè, àjọ̀dún àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Òwò tò gbòde ni Ilé-apejọ àti gbogbo ohun èlò rẹ Ọpọlọpọ àwọn ti o jade ni ilé-iwé giga ti kò ri iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ si kọ́ṣẹ́ bi wọn ti ńwé gèlè, rán aṣọ, àsè sisè àti iṣẹ́ Olù-palèmọ́ ayẹyẹ nígbàtí ẹlẹgbẹ́ wọn ni Òkè-òkun ńṣe àṣe yọri ninú ẹ̀kọ-ijinlẹ Fún akiyesi, ilé-àpèjọ pọ̀ ju ilé-ìkàwé lọ Ọpọlọpọ àwọn ti ó ńṣe àpèjẹ yi ló ńjẹ igbèsè lati ṣé Omiran kò ni ri owó ilé-iwé ọmọ san lẹhin ìsìnkú, tàbi ki wọn ma ri owó lati pèsè oúnjẹ tàbi aṣọ fún ọmọ-tuntun ti wọn ná owó rẹpẹtẹ lati kó jade Bawo ni a ti lè ṣe àlàyé pé kò si owó lati rán ọmọ lọ si ilé-iwé tàbi bèrè pé ki Ìjọba Òkè-òkun wá pèsè iná mọ̀nàmọ́ná, omi, ilé-ìwòsàn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ fún àwọn ti Inú rẹ dùn jù ni àgbáyé Fún idi eyi, Yorùbá ẹ jẹ́ ki á ronú lati ṣe àyipadà Ọ̀pọ̀ owó ti Ọlọ́rọ̀ fi ńṣe ìsìnkú wúlò fún alàyè lọ, nípa pi pèsè ilé-iwé, omi-ẹ̀rọ, ọ̀nà, ilé-ìkàwé ni orúkọ olóògbé ju ki gbogbo owó bẹ́ẹ̀ lọ fún ayẹyẹ Òwe Yorùbá ti o ni Bi ikú ilé ò pani, tòde ò lè pani bá ọ̀pọ̀ iṣẹ̀lẹ̀ ti o ńṣẹlẹ̀ nítorí ìfẹ́ owó ti ó gbòde láyé òde òní mu Ọmọ, ẹbi tabi alábagbe ńdarapọ̀ mọ olè, gbọ́mọgbọ́mọ, oníjìbìtì lati fi ipá gba owó lọ́wọ́ ẹbi ti wọn bá mọ̀ tabi rò pé ó ni owó púpọ̀ Fún àpẹrẹ, ẹni ti o mba enia gbé ló mọ ohun ti enia ni Bi ọmọ, ẹbi tabi alábagbe wọnyi bá ni ojúkòkòrò wọn á darapọ̀ mọ olè lati gbé ẹrù tàbi owó pẹ̀lú ipá Ọpọlọpọ obinrin ti o ni ohun ẹ̀ṣọ́ bi wúrà àti fàdákà ni alábagbe ma ńdarapọ mọ olè lati wá gbé ohun ẹṣọ yi fún tita lati di olówó ojiji Àpẹrẹ pàtàkì miran ni àwọn òṣìṣẹ́ ilé-owó, ilé iṣẹ́ Ijọba àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ti wọn darapọ̀ lati ja ilé iṣẹ́ wọn Ọ̀pọ̀ igbà ni àṣiri ọmọ, ẹbi tàbi alábagbe tó darapọ̀ mọ́ olè, gbọ́mọgbọ́mọ, òṣìṣẹ́ àti awọn oni iṣẹ́ ibi tókù ma ńtú, ninu ìjẹ́wọ́ awọn oníṣẹ́ ibi wọnyi nígbàtí ọwọ́ Ọlọpa bá tẹ̀ wọ́n Nítorí eyi, ó yẹ ki a ma ṣọ́ra Ni igba kan ri, Àmọ̀tékùn ni àwọ̀ dúdú ti ó jọ̀lọ̀, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ kan, Àmọ̀tékùn wá oúnjẹ òòjọ́ rẹ lọ Ó dé ahéré kan, ó ṣe akiyesi pe obinrin kan ńwẹ̀, inú rẹ dùn púpọ̀ pé òhún ti ri oúnje O lúgọ de asiko ti yi o ri àyè pa obinrin yi fún oúnjẹ Yorùbá ni Ọ̀pá tó wà lọ́wọ́ ẹni la fi npa ejò Nígbàtí obinrin yi ri Àmọ̀tékùn, pẹ̀lú ìbẹ̀rù, ó fi igbe ta, ó ju kàrìnkàn ti ó fi ńwẹ̀ pẹ̀lú ọṣẹ híhó inú rẹ lù Àmọ̀tékùn fi eré si ṣùgbọ́n, gbogbo ọṣẹ ti ó wà ninu kànrìnkàn ti ta àbàwọ́n si ara rẹ lati ori dé ẹsẹ̀ rẹ, eleyi ló sọ Àmọ̀tékùn di alámì tó-tò-tó lára titi di ọjọ́ oni Yorùbá ma nlo àwọn àròsọ itàn wọnyi lati kọ́ àwọn ọmọdé ni ẹ̀kọ́ Yorùbá ni Ẹni ti ó bá dákẹ́, ti ara rẹ á ba dákẹ́, nítorí eyi ẹ̀kọ́ pàtàkì ti a ri ninu itàn àròsọ yi ni pé, kò yẹ ki enia fi ìbẹ̀rù dúró lai ṣe nkankan ti ewu bá dojú kọni ṣùgbọ́n ki á lo ohun kóhun ti ó bá wà ni àrọ́wótó lati fi gbèjà ara ẹni Kòkòrò jẹ́ ohun ẹ̀dá kékeré tó ni ìyẹ́, ti ó lè fò, òmíràn kò ni iyẹ́, ṣugbọn wọn ni ẹsẹ̀ mẹfa Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ, àwòrán àti pi pè ni ojú ewé wọnyi Ọpọlọpọ ọmọ Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ si tijú lati jẹ orúkọ ti òbí fi èdè Yorùbá sọ wọn Èwo ni ká kọ Bayọ ni Bayor, Fẹmi ni Phemmy, Tọlani ni Thorlani – kilo njẹ bẹ́ẹ̀ Nígbàtí ẹni to ni orúkọ bá ńbàjẹ bawo ni àjòji ṣe lè pe orúkọ na dada Lẹhin ọdún pipẹ́ itumọ̀ orúkọ ti wọn ba jẹ yi a sọnù Ẹni ti kò bámọ̀ itàn ara rẹ̀, wọn á pe lorúkọ ti ki ṣe tirẹ, á si dáhùn Á gbọ́ ti igbà òwò burúkú Òwò Ẹrú, ti ilú tó lágbára ra àwọn enia bi ẹni ra ohun ini Ni àsikò yi, bi wọn bà kó enia lẹ́rú, olówó rẹ á fun lórúkọ nítorí ko ma ba ranti ibi ti ó ti ḿbọ̀ Eleyi jẹ ki ó ṣòro fún ẹrú lati mọ ibi ti wọn ti wa lẹhin ti òwò ẹrú pari Òwe Yorùbá ni Ilé làńwò kátó sọmọ lórúkọ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ maṣe jẹ́ki ẹ̀yà àti èdè Yorùbá parẹ́ Orúkọ ẹni ni ifihàn ẹni, ao ni parẹ máyé o Ẹ̀gẹ́ fi ara jọ Iṣu nítorí àwọn mejeeji jẹ oúnjẹ ti ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá ti wọn ńkọ ebè fún lati gbin Wọn ma nwa wọn lati inú ebè ti wọn bá ti gbó, wọn ni eèpo ti wọn ma ḿbẹ Gbaguda ni wọn fi ńṣe gaàrí, bẹni wọn lè ló fún oriṣiriṣi oúnjẹ miran bi wọn ti lè lo iṣu, ṣùgbọ́n oúnjẹ bi iyán ati àmàlà mú iṣu gbayì ju ẹ̀gẹ́ lọ Fún ẹ̀kọ́ yi, ohun ti a lè fi iṣu ṣe yàtọ̀ si, iyán àti àmàlà ni a fẹ́ sọ A lè fi iṣu din dùndú, tàbi se lati fi jẹ ẹ̀wà ẹ̀fọ́ rirò ata, tàbi fi se àṣáró Ìjọba Ìlú-Ọba kò bere lọwọ ará ilú ki wọn tó ṣe ìdàpọ̀ yi, wọn ṣe fún irọ̀rùn ọrọ̀ ajé ilú ti wọn ni Yorùbá ni À jọ jẹ kò dùn bi ẹni kan kò ri Nitòótọ, Ijọba Ilu-Ọba ti fún orilẹ̀ èdè Nàíjíríà ni ominira, ṣùgbọ́n èrè idàpọ̀ ti ará ilú kò kópa ninu rẹ kò tán Gẹgẹbi Olóyè Ọbafẹmi Awolọwọ ti sọ nígbàtí wọn ńṣe àdéhùn fún ominira pe ominira ki ṣe ni ti orúkọ ilú lásán, ṣùgbọ́n ominira fún ará ilú A ṣe akiyesi pe lẹhin ìdàpọ̀ ọgọrun ọdún, orilẹ̀ èdè ko ṣe ikan Yorùbá ni A kì í tó́ó báni gbé, ká má tòó ọ̀rọ̀-ọ́ báni sọ Gẹgẹbi òwe yi, ki ṣe ki kó ọ̀kẹ́ aimoye owó lati ṣe àjọyọ̀ ìdàpọ̀ ti ará ilú kò kópa ninu rẹ ló ṣe pàtàkì, bi kò ṣé pé ki a tó ọ̀rọ̀ bára sọ Yorùbá ni Ọ̀rọ̀ la fi dá ilé ayé Ẹ̀kọ́ púpọ̀ ni enia lè ri kọ́ ni irin àjò A lè rin irin àjò fún ìgbà díẹ̀ tàbi pípẹ́ lati bẹ ilú náà wò tàbi lati lọ tẹ̀dó si àjò Gbogbo ọ̀nà yi ni Yorùbá ti lọ lati dé Ìlú-Ọba Àṣepọ̀ laarin ará Ìlú-Ọba àti Yorùbá ti lè ni ọgọrun ọdún, nítorí eyi, kò si ibi ti enia dé ni Ìlú-Ọba ni pàtàkì àwọn Olú-Ìlú, ti kò ri ẹni ti ó ńsọ èdè Yorùbá tàbi gbé irú ilú bẹ A ṣe akiyesi pé lati bi ọdún mẹwa sẹhin, àṣepọ̀ laarin ọmọ Yorùbá ni Ìlú-Ọba din kù Ni ìgbà kan ri, bi ọmọ Yorùbá bá ri ara, wọn a ki ara wọn Òwe Yorùbá ni Ibi ti a ngbe la nse, bi a bá dé ìlú adẹ́tẹ̀ a di ìkúùkù, àwọn ọ̀nà ti a lè fi ṣe ibi ti a ngbe Ki ka ìwé nípa àṣà àti iṣẹ ìlú ti a nlọ ninu ìwé tàbi ṣe iwadi lori ayélujára, wiwa ibùgbé, lọ si Ilé-Ìjọ́sìn, Ọjà, Ọkọ̀ wiwọ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ẹ fi ojú sọ́nà fún àlàyé lori àwọn ọ̀nà ti enia lè lò lati tètè fi idi kalẹ̀ ni àjò Yorùbá jẹ́ ẹ̀yà ti ó wà ni Ìwọ̀-oòrùn orilẹ̀ èdè Nàíjíríà Bi Yorùbá ti fẹ́ràn igbádùn tó, bẹ ni wọn fẹ́ràn òwò ṣiṣe àti ẹ̀kọ́ kikọ́ Ọba, Olóyè, Ọlọ́rọ̀ àti aláìní ilẹ̀ Yorùbá ló fẹ́ràn àti rán ọmọ wọn lọ si ilé-iwé bi àwọn fúnra wọn kò ti ẹ lọ si ilé-iwé Eleyi jẹ ki Yorùbá pọ kà kiri àgbáyé pàtàkì ni Àríwá Nàíjíríà Nibi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Yorùbá ti fẹ́ràn iwé-kikà ni ẹ̀yà miràn ti fi ẹsin bojú lati ṣe àtakò iwé kikà, pàtàkì àwọn ti o ni A ò fẹ́ iwé – Boko Haram Àwọn ti ó ni àwọn kò fẹ́ lọ si ilé-iwé bẹ̀rẹ̀ si pa ọmọ àwọn ti ó fẹ́ lọ Wọn kò dúró lóri ọmọ ilé-iwé nikan, wọn ńpa enia bi ẹni pa ẹran ni ọjà, oko, ilú, ọ̀nà àti gbogbo ibi ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilú ni òkè-Ọya pàtàkì ni ilú Borno Yorùbá ni Bi onilé bá ti ńfi àpárí iṣu lọ àlejò, ilé tó lọ Ki ṣe àpárí iṣu nikan ni wọn fi ńlọ àjòjì ni òkè-ọya ikú òjiji ni Àini ifọkàn balẹ̀ kò lè jẹ́ ki àjò ò pé Lati igbà ti ẹni ti ó so iná ajónirun mọ́ra ti bẹ̀rẹ̀ si pa enia bi ẹni pẹran ni ilé ijọsin – pàtàkì ti onígbàgbọ́, ọjà, áàarín ilú, abúlé àti ilé-iwé ni àjò kò ti pé mọ́ Ìròyìn kàn ni ọjọ́ kẹdogun oṣù kẹrin ọdún Ẹgbàálemẹ́rìnlá, pe wọn ti tún bẹ̀rẹ̀ si ji ọmọ ilé-iwé gbé – ó lé ni ọgọrun ọmọ obinrin ti wọn fi ipá ji wọn gbé, mẹ́rìnlá ni ó ri àyè sá mọ́ ajínigbé lọ́wọ́, òbi àwọn ti ó kù wà ninú ìrora A lè fi òwe Yorùbá ti ó ni Ẹni àjò ò pé, kó múra ilé gba àwọn Yorùbá ti ó wà ni òkè-ọya ni ìyànjú pé ki wọn bẹ̀rẹ̀ si múra ilé, ki wọn ma ba pàdánù ẹmi, ó sàn ki enia pàdánù owó ju ẹ̀mi lọ Ni aiyé àtijọ́, ẹsin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ló dàbi ọkọ̀ igbàlódé ti wọn ńpè ni mọ́tò Ẹni ti ó jẹ́ ọlọ́rọ̀, ló lè ni ẹsin tàbi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ẹsẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ńrin irin àjò Ìtàn yi dá ló̀ri Bàbá àti ọmọ rẹ ti wọn ńsin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Wọn múra lati rin irin àjò Gẹ́gẹ́ bi àṣà Yorùbá lati bu ọ̀wọ̀ fún àgbà, Bàbá ló gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọmọ rẹ bẹ̀rẹ̀ si rin tẹ̀lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Àwọn enia ti o ri wọn ni Bàbá, iwọ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọmọ ńrin ni ilẹ̀ Nítorí ọ̀rọ̀ yi, Bàbá bọ́ silẹ̀, ó gbé ọmọ rẹ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Àwọn aiyé tún ri wọn ni Bàbá ńrin nilẹ̀, ọmọ ńgun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ti dàgbà, ṣùgbọ́n tori ẹnu aiyé, Bàbá àti ọmọ bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn Wọn ko ti rin jinà nígbàtí àwọn ti ó ri wọn tún ni Ẹ wo Bàbá àti ọmọ tó fẹ́ pa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Nítorí àti tẹ́ aiyé lọ́run, Bàbá àti ọmọ bọ́ silẹ̀, wọn bẹ̀rẹ̀ si fi ẹsẹ̀ rin tẹ̀lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Àwọn arin irin àjò yókù tún ri wọn, wọn ni Ẹrú aiyé ni àwọn eleyi, bawo ni wọn ṣe lè ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ki wọn ma fi ẹsẹ̀ rin Nígbàtí Bàbá ti gbìyànjú titi, ti kò mọ ohun ti ó tún lè ṣe mọ́, lati tẹ́ aiyé lọ́rùn ni ó ránti ọ̀rọ̀ Yorùbá tó ni Kò si ọgbọ́n ti o lè dá, kò si iwà ti o lè hù, ti o lè fi tẹ́ aiyé lọ́rùn Yorùbá ni Ẹni à ḿbá ra ọjà là ńwò, a ki wó ariwo ọjà̀ Lára nkan ti itàn yi kọ́ wa ni pé ohun ani là ńlò, ibi ti à ńlọ ni ká dojú kọ lai wo ariwo ọjà àti pé enia ni lati ni ọkàn tirẹ̀ nítorí kò si ẹni ti ó lè tẹ́ aiyé lọ́rùn Ẹ gbọ bi ògúná gbòngbò ninú àwọn ọ̀gá ninú olórin ilẹ̀ Yorùbá àti ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú – Chief Ebenezer Fabiyì ti a mọ si Olóyè Adarí ti fi itàn yi kọrin Àkàrà jẹ ikan ninu ounjẹ aládùn ilẹ̀ Yorùbá A lè fi àkàrà jẹ ẹ̀ko, fi mu gaàrí tabi jẹ fún ìpanu Ki ṣe gbogbo enia ló mọ àkàrà din, awọn enia ma nfẹran ẹni ti ó ba mọ àkàrà din Àti ọmọdé àti àgbà ló fẹ́rán àkàrà Awọn ọmọde ma nkọrin bayi Ki ṣe enia nikan ló fẹ́ràn àkàrà, Àjàpá naa fẹ́ràn àkàrà, ṣùgbọ́n kò ri owó raa, nítorí èyi Ojú ni Àjàpá fi nri àkàrà, ètè rẹ ko baa Àjàpá wá ronú ọgbọ́n ti ó lè dá lati pèsè àkàrà fún òhun àti idilé rẹ Ó ronú bi wọn ti lè dá ẹ̀rù ba ọmọ alákàrà ki ó lè sá fi igbá àkàrà, rẹ silẹ̀ Ó gbé agọ̀ wọ̀, ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ fi pápá́ bora Bi alákàrà ba ti kiri kọjá, Àjàpá a bẹ si iwájú ọmọ alákàrà, wọn a ma ko orin bayi Ẹ̀rù ba alákàrà, á da àkàrà dà nù Àjàpá àti ẹbí rẹ á bẹ̀rẹ̀ si kó àkàrà Yorùbá ni Wọ́n mú olè lẹẹkan, ó ni ohun ò wá ri, tani fi ọ̀nà han olè Ọmọ alákàrà sunkún lọ si ilé, inú Ìya-alákàrà kò dùn si ọmọ rẹ nítorí o pàdánù àkàrà àti owó ti o yẹ ki ó pa Kò gba ìtàn ọmọ rẹ̀ gbọ́, nítorí náà, ó gbé àkàrà fún ni ọjọ́ keji ati ọjọ́ kẹta, ọmọ tún padà pẹ̀lú ẹkún Ohun fúnra rẹ̀ tẹ̀lé ọmọ rẹ̀, iwin tún yọjú, àwọn mejeeji sá eré padà si ìlú lai ranti gbé igbá àkàrà Ìyá alákàrà gba ọ̀dọ̀ Ọba àti àgbà ìlú lọ lati sọ ohun ti ojú wọn ri Ọba pe awọn òrìṣà ìlú lati ṣe iwadi ohun ti ó fẹ́ ba ọrọ̀ ìlú jẹ yi Ninu gbogbo òrìsà, Ọ̀sanyìn nikan ló gbà lati yanjú ọ̀rọ̀ yi Ìyá alákàrà tungbe àkàrà fún ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun àti Ọsanyin tẹ̀lé Bi alákà̀rà ti bẹ̀rẹ̀ si polówó, Àjàpá tún jade gẹgẹ bi iṣe rẹ̀ Yorùbá ni Ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ́ kan ni ti olóhun Ìyá alákàrà àti ọmọ rẹ̀ tún méré, ṣùgbọ́n Ọ̀sanyin ti o fi ara pamọ́ dúró lati wo ohun ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀ Àjàpá àti àwon idile rẹ̀ jade nwọn bọ ohun ti nwọn fi bora silẹ̀ lati tún bẹ̀rẹ̀ si kó àkàrà Orí ti Àjàpá yọ jade lati jẹ àkàrà, Ọ̀sanyin fọ igi ẹlẹgun mọ lórí, awọn ẹbi rẹ̀ sálọ Ọ̀sanyin gbé òkú Àjàpá lọ si ọ̀dọ̀ Ọba Inú ará ìlú dùn nítorí àṣiri olè tú Ọba pàṣẹ pe Àjàpá ni ki nwọn bẹrẹ fi rúbọ si Ọ̀sanyin Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pe ojúkòkòrò kò lérè, bó pẹ́, bóyá àṣírí olè á tú Ikú lèrè ẹ̀ṣẹ̀ – Àjàpá pàdánù ẹ̀mí nítorí àkàrà Gbé epo kaná Kó èlò bi ẹ̀jà tútù tàbi gbigbẹ, edé, pọ̀nmọ́ sinú ikòkò epo-pupa yi Fi iyọ̀ àti iyọ̀ igbàlódé àti omi si inú ikòkò yi lati se omi ọbẹ ìkọ́kọrẹ́ Fọ Iṣu Ewùrà kan Bẹ Ewùrà yi Fi iyọ̀ bi ṣibi kékeré kan po ewùrà ri-rin yi Lẹhin pi pò, dá ewùrà pi pò yi sinú omi ọbẹ̀ ti a ti sè fún bi iṣẹ́jú mẹdogun Rẹ iná rẹ silẹ̀, se fún bi ogún iṣẹ́jú Lẹhin eyi bu fún jijẹ Ẹbi Iṣu ni Ewùrà ṣùgbọ́n a lè pe Iṣu ni ẹ̀gbọ́n Ewùrà nítorí ohun ti a lè fi Iṣu ṣe gbayì laarin gbogbo Yorùbá ju eyi ti a lè fi Ewùrà ṣe Ọpọlọpọ Yorùbá fẹran oúnjẹ òkèlè bi iyán àti àmàlà ti o gbayì ni ọpọlọpọ ilẹ̀ Yorùbá Ohun miran ti wọn ńfi iṣu ṣe ni Àsáró, iṣu sisè, iṣu sí-sun, iṣu dín-dín àti àkàrà iṣu Oúnjẹ ti ó wọ́po laarin àwọn Ijẹbu ti a ńfi Ewùrà ṣe ni Ìfọ́kọrẹ́ tàbi bi àwọn ọmọdé ti ma ńpe Ìkọ́kọrẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ Yorùbá na fẹ́ràn Ìfọ́kọrẹ́ A lè jẹ Ìfọ́kọrẹ́ lásá̀n, àwọn miran lè fi jẹ ẹ̀bà A tún lè lo Ewùrà lati ṣe Ọ̀jọ̀jọ̀ Ọ̀pọ̀ Ewùrà sisè kò dùn lati jẹ bi iṣu gidi Ẹ ṣe àyẹ̀wò bi a ti ńṣe Ìfọ́kọrẹ́ àti Ọ̀jọ̀jọ̀ lójú iwé yi Ẹ ṣe àyẹ̀wò bi a ti ńṣe Ìkọ́kọrẹ́ àti Ọ̀jọ̀jọ̀ lójú iwé yi Ọbẹ̀ ti enia lè yára sè ju ọbẹ̀ ilá ni, nítorí bi a bá ni àpọ̀n kíkù nile, a din àkókò ti ó yẹ ki enia fi rẹ́ ilá kù Ọbẹ̀ ti a lè fi owó díẹ̀ sè ni Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni Ẹ jáwọ́ lápọ̀n ti kò yọ̀, ẹ lọ dá omi ilá kaná jẹ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú fún ẹni ti ó ba ńṣe iṣẹ́ ti kò ni èrè tàbi ìlọsíwájú, pé ki irú ẹni bẹ gbiyànjú àti ṣe iṣẹ́ miran ki ó má ba fi àkókò ṣòfò Ẹ yẹ èlò àti sise ọbẹ̀ àpọ̀n ni ojú iwé yi Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni Àlébù ki ṣe ẹ̀gàn tàbi agọ̀, ṣùgbọ́n, ẹ̀gàn àti agọ̀ ni fún ẹni ti ojú rẹ fọ́ si àlébù ara rẹ Irú ẹni bẹ́ẹ̀, kò lè ri àtúnṣe tàbi sọ àlèbú yi di ohun ini Ninú ìtàn bi Àjàpá ti sọ Ẹlẹ́dẹ̀ di ọ̀bùn ti a mọ̀ si titi di oni, Àjàpá jẹ́ ẹranko ti kò lè yára rin tàbi ni agbára iṣẹ́ àti ṣe lówó, ṣùgbọ́n ó ni ọgbọ́n lati bo àlébù rẹ Yorùbá ni Alágbára má mèrò, baba ọ̀le, Ọgbọ́n ju agbára Àjàpá́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹwẹ, nígbàtí Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ alágbá̀ra ti kò mèrò Kò si ohun ti Àjàpá lè ṣe lai ni idi tàbi ọgbọ́n àrékérekè, nítorí eyi, ó sọ ara rẹ di ọ̀rẹ́ Ẹlẹ́dẹ̀ nítorí gbogbo ẹranko yoku ti já ọgbọ́n rẹ Ẹlẹ́dẹ̀ kò fi ọgbọ́n wá idi irú ọ̀rẹ́ ti Àjàpá jẹ́ Laipẹ, Àjàpá lọ yá owó lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dẹ̀ pẹ̀lu àdéhùn pe ohun yio san owó na padà ni ọjọ́ ti ohun dá Ẹlẹ́dẹ̀ rò pé ọ̀rẹ́ ju owó lọ, ó gbà lati yá Àjàpá lówó nítorí àdéhùn rẹ Nígbàtí ọjọ ti Àjàpá dá pé, Ẹlẹ́dẹ̀ reti titi ki ó wá san owó ti ó yá, ṣù̀gbọn Àjàpá kò kúrò ni ilé rẹ nítorí ó mọ̀ pé ohun kò ni owó́ lati san Àjàpá fi ohun pẹ̀lẹ́ ṣe àlàyé pé bi ohun ti fẹ́ ma kó owó lọ fún Ẹlẹ́dẹ̀ ni olè dá ohun lọ́nà, ti wọn gba gbogbo owó lọ Inú Ẹlẹ́dẹ̀ kò dùn nítorí kò gba iṣẹ̀lẹ̀ yi gbọ́, ṣùgbọ́n ó gba nígbàtí Àjàpá tún dá ọjọ́ miran lati san owó na Bi Ẹlẹ́dẹ̀ ti kúrò ló bá aya rẹ Yáníbo dìmọ̀pọ̀ bi ohun kò ti ni san owó padà Ó ni bi ọjọ́ bá pé, bi Yáníbo bá ti gbọ́ ìró Ẹlẹ́dẹ̀, kó yi ohun padà, ki ó bẹrẹ si lọ ẹ̀gúsí ni àyà ohun lai dúró bi Ẹlẹ́dẹ̀ bá wọlé bèrè ohun Ni ọjọ́ ti Àjàpá dá pé, Ẹlẹ́dẹ̀ dé lati gba owó rẹ, Yáníbo ṣe bi ọkọ rẹ ti wi Ẹlẹ́dẹ̀ fi ibinu gbé ọlọ àti ẹ̀gúsí sọnù si ẹrọ̀fọ̀ ti ó wá ni ìtòsí lai mọ̀ pé Àjàpá ni ọlọ yi Yáníbo fi igbe ta titi ọkọ rẹ fi wọlé Àjàpá yọ ara rẹ̀ kúrò ninú ẹrọ̀fọ̀, ó nu ara rẹ̀, ó ṣe bi ẹni pé ohun kò ri Ẹlẹ́dẹ̀ nígbàtí ó délé Ó bèrè ohun ti ó fa igbe ti Yáníbo ńké Yáníbo ṣe àlàyé Yorùbá ni Ọ̀bùn ri ikú ọkọ tìrọ̀ mọ́, ó ni ọjọ́ ti ọkọ ohun ti kú ohun ò wẹ̀ Àjàpá ri ohun ṣe àwá-wi, ó sọ fún Ẹlẹ́dẹ̀ pé ọlọ ti ó gbé sọnù ṣe pàtàkì fún idilé àwọn, nítorí náà ó ni lati wá ọlọ yi jade ki ohun tó lè san owó ti ohun yá Ẹlẹ́dẹ̀ wọnú ẹrọ̀fọ̀ lati wá ọlọ idile Àjàpá Lati igbà yi ni Ẹlẹ́dẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ si fi imú tú ẹrọ̀fọ̀ titi di ọjọ́ oni Ni àṣà Yorùbá, ni ayé àtijọ́, ọjọ́ keje ni wọn ńsọmọ obinrin ni orúkọ, ọjọ́ kẹsan ni ti ọmọ ọkùnrin, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ọjọ kẹjọ ni wọn sọ gbogbo ọmọ lórú̀kọ Yorùbá ki sọmọ lórúkọ ni ọjọ́ ti wọn bi, ṣùgbọ́n Yorùbá ti ó bá bimọ si òkè-òkun lè fún ilé-igbẹbi lórúkọ ọmọ gẹgẹ bi àṣà òkè-òkun ki wọn tó sọmọ lórúkọ Òwe Yorùbá ni Ilé làńwò, ki a tó sọmọ lórúkọ nítorí eyi, Bàbá àti Ìyá yio ronú orúkọ ti ó dara ti wọn yio sọ ọmọ ni ọjọ́ ikómọ Orúkọ Yorùbá lé ni ẹgbẹ-gbẹrun, àwọn orúkọ yi yio jade ni ipasẹ̀ akiyesi iṣẹ̀lẹ̀ ti o ṣẹlẹ̀ ni àsikò ti ọmọ wa ni ninú oyún, ọjọ́ ibi ọmọ, orúkọ ti ó bá idilé tabi ẹsin àtijọ́ àti ẹsin igbàlódé mu A o ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ igbalode àti àwọn orúkọ ibilẹ ti ó ti fẹ ma parẹ A o bẹrẹ pẹlu orukọ ti o wọpọ ni idile Ọlá, Ọba, Olóyè àti Akinkanjú ni àwùjọ ni ayé òde òni Ọlá ninú orúkọ Yorùbá ki ṣe owó àti ohun ini nikan, Yorùbá ka ilera si Ọlà Ọmọ bibi ni ewu púpọ̀, nítorí eyi ni Yorùbá fi ma nki ìyá ọmọ kú ewu Ni ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ tàbi ìkómọ, Bàbá, Ìyá, ẹbi àti ọ̀rẹ́ òbí ọmọ tuntun á fi ìdùnnú hàn nípa ṣíṣe ọpẹ́ pàtàkì fún Ọlọrun Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ wọnyi ti òbí lò lati fi ẹmi ìmoore hàn Òwe yi fi ara han ni itan ìyàwó Aṣojú-ọba, ti a ò pè ni Tinumi pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo, ọkùnrin ti a mọ̀ si Mofẹ́ Mofẹ́ dàgbà lati fẹ obinrin Ó̀ yan obinrin ti à ńpè ni Àyànfẹ́ ni ìyàwó àfẹ́sọ́nà Nígbàtí ó mú Àyànfẹ́ lọ han àwọn òbi rẹ, Bàbá Mofẹ́ gba Àyànfẹ́ tọwọ́-tẹsẹ̀, ṣùgbọ́n iyá Mofẹ́ fi àáké kọ́ri pé ọmọ ohun kò ni fẹ́ Àyànfẹ́ Wọn bẹ̀rẹ̀ idi ti kò ṣe fẹ́ ki ọmọ ohun fẹ ẹni ti ó múwá, Tinumi kò ri àlàyé ṣe ju pé ohun kò fẹ́ ki ọmọ ohun fẹ́ Àtọ̀hún rin wa – ọmọ ti kò ni iran Ọmọ rẹ naa fi àáké kòri pé ẹni ti ohun ma fẹ ni Àyànfẹ́ Tinumi sọ àfẹ́sọ́nà ọmọ rẹ di orogún, gbogbo ibi ti ó bá ti pàdé Àyànfẹ ni ibi àjoṣe ẹbi ni ó ti ḿbajà pé ki ó dẹ̀hin lẹhin ọmọ ohun Àyànfẹ́ lé ọmọ rẹ titi ṣùgbọ́n ó kọ̀ lati dẹhin Lẹhin ọdún marun ti Mofẹ́ àti Àyànfẹ́ ti ńṣe ọ̀rẹ́, iwé jade pé wọn gbé Bàbá Mofẹ́ Gẹgẹ bi Aṣojú-Ọba lọ si Òkè-òkun Bàbá ṣètò bi ọmọ àti ìyàwó ti ma tẹ̀lé ohun Ọmọ kọ̀ pé ohun kò lọ pẹ̀lú òbi ohun ti àfẹ́sọ́nà ohun kò bá ni tẹ̀lé àwọn lọ Bàbá gbà pé ọmọ ohun ti tó fẹ́ ìyàwó, wọn ṣe ètò igbéyàwó fún Mofẹ́ àti àfẹ́sọ́nà̀ rẹ Lẹhin ti Mofẹ́ àti Àyànfẹ́ ṣe ìyàwó tán, wọn tẹ̀lé Bàbá àti Ìyá wọn lọ si Òkè-okun lati má jọ gbé Àrùn ara Tinumi, aya Aṣojú-ọba bẹ̀rẹ̀ si han nítorí ó sọ ìyàwó ọmọ rẹ di orogún Nígbàtí ọkọ rẹ ri àlébù yi, ó pinu lati wa orogún fun Tinumi nítorí ai ni orogún ni ó ṣe sọ aya ọmọ rẹ di orogún Gẹgẹ bi a ti mọ, igbéyàwó ibilẹ̀ kò ni ki ọkùnrin ma fẹ ìyàwó keji Ó jẹ èrè iwà burúkú àti ìgbéraga Ọkùnrin kan pẹ̀lú ìyàwó púpọ̀ wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá Àwọn obinrin ti ó bá́ fẹ́ ọkọ kan naa ni à ńpè ni Orogún Ìwà oriṣiriṣi ni ó ma ńhàn ni ilé olórogún, àrù̀n ìyàwó ti ó ńjalè, purọ́, ṣe àgbèrè, aláisàn, ti ó ńṣe òfófó, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, lè má hàn bi ó bá jẹ́ obinrin kan pẹ̀lú ọkọ rẹ ni ó ńgbe gẹ́gẹ́ bi ti ayé ode oni Bi ìyàwó bá ti pé méjì, mẹta, bi àrù́n yi bá hàn si ìyàwó keji, èébú dé, pàtàkì ni àsikò ijà Ni ẹ̀sin ibilẹ̀, oye ìyàwó ti ọkùnrin lè fẹ́, ko niye, pàtàkì Ọba, Olóyè, Ọlọ́rọ̀ àti akikanjú ni àwùjọ Bi àwọn ti ó ni ipò giga tabi òkìkí ni àwùjọ kò fẹ́ fẹ́ ìyàwó púpọ̀, ará ilú á fi obinrin ta wọn lọ́rẹ Ẹ̀sin igbàlódé pàtàkì, ẹ̀sin igbàgbọ́ ti din àṣà ikó-binrin-jọ kù Òfin ẹlẹ́sin igbàgbọ́ ni ọkọ kan àti aya kan Bi o ti jẹ́ pé ẹ̀sin Musulumi gbà ki Ọkùnrin lè fẹ́ ìyàwó titi dé mẹrin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin Musulumi igbàlódé ńsá fún kikó ìyàwó jọ Fẹlá Kúti fẹ́ ìyàwó mẹta-din-lọgbọn ni ọjọ kan Yorùbá ni Òriṣà òkè jẹ́ ki npé méjì obinrin kò dé nú Inú obinrin ti wọn fẹ́ ìyàwó tẹ̀lé kò lè dùn dé inú, nítorí eyi, kò lè fi gbogbo ọkàn rẹ tán ọkọ rẹ mọ, owú jijẹ á bẹ̀rẹ̀ ìyàwó kékeré lè dé ilé ri àbùkù ọkọ ti iyálé mú mọ́ra Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé oló-rogún kiki ijà àti ariwo laarin àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ naa Diẹ̀ ninú ọkùnrin ti ó fẹ́ ìyàwó púpọ̀ ló ni igbádùn Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin ti ó kó obinrin jọ ni ó ńsọ ẹ̀mi wọn nù ni ọjọ́ ai pẹ́ nítorí ai ni ifọ̀kànbalẹ̀ àti àìsàn ti bi bá obinrin púpọ̀ lò pọ̀ lè fà Nítorí eyi, ọkùnrin ti ó bá fẹ́ kó ìyàwó jọ nilati múra gidigidi fun ohun ti ó ma gbẹ̀hìn àṣà yi Yorùbá ni Ọmọ ẹni kò lè burú titi, ká fi fún Ẹkùn pa jẹ, ki ṣe bi ti obinrin Sudan – Mariam Yahia Ibrahim ti wọn gbé si ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú oyún lati dúró de idájọ́ ikú lẹhin ọmọ bibi nítorí ẹ̀sìn Ohun pẹ̀lú ọmọ ti ó ti bi tẹ́lẹ̀ ni wọn gbé jù si ẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn pé kò yẹ ki ó fẹ́ ìgbàgbọ́ lábẹ́ òfin Sharia Lábẹ́ òfin yi, ọkùnrin Ìmàle lè fẹ́ obinrin ni ẹ̀sìn miran, ṣùgbọ́n obinrin wọn kò ni ẹ̀tọ́ lati fẹ́ ẹni ti ó bá ṣe ẹ̀sìn miran Kò si bi ẹni ti ó fa ọmọ rẹ̀ silẹ̀ nítorí ó fẹ́ ẹlẹ́sìn miran ti lè sọ pé ohun ni òtitọ́ ninú gbàwìn ìkà Bawo ni enia ṣe lè pa ẹni-keji nítorí ẹ̀sìn Ìkà ti wà ninú irú àwọn bayi ki wọn to gba ẹ̀sìn, wọn kan fi ẹ̀sìn bojú ṣe ìkà ni Àjà ni wọn fi ḿbọ̀ Ògún ki ṣe enia Yorùbá ni A ki fi ọmọ Ọrẹ̀, bọ Ọrẹ̀, òwe yi túmọ̀ si pe abòriṣà Yorùbá kò jẹ́ fa ọmọ rẹ silẹ fún ikú nítorí ó yà kúrò ninú ẹ̀sin ibilẹ̀ Ìròyìn jade pé Mariam Yahia Ibrahim ti bi ọmọ si ẹ̀wọ̀n, a ri ninú ẹbi rẹ ti o ke pe ki won fi ikú si-so pá ti ó bá kọ̀ pé ohun kó padá si ẹ̀sìn Ìmàle Gbogbo àgbáyé ḿbẹ̀ àwọn Òṣèlú Sudan ki wọn tú obinrin àti àwọn ọmọ rẹ̀ silẹ̀ nítorí irú ẹjọ́ oró yi, kò tọ̀nà ni ayé òde òni Ọ̀pọ̀ ti ó ni ipò ni àwùjọ ni ó fi iwà ikà ba ipò wọn jẹ Ìròyìn bi Olóògbé Jimmy Savile ti fi iwà burúkú ba iṣẹ́ ribiribi ti ó ṣe nípa pi pa owó fún ọrẹ-àánú ni ó ńlọ lọ́wọ́-lọ́wọ́ Iṣẹ́ ibi ti ó ṣe ni igbà ayé rẹ fihan pé O ni ikù ló mọ̀ ikà Gẹ́gẹ́ bi iwadi ti o jáde lẹhin ikú Olóògbé yi, ó lo ipò rẹ ni àwùjọ lati bá ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta obinrin ni àṣepọ̀ ni ọ̀nà ti kò tọ́ Òwe Yorùbá ti ó ni Ẹni ti o ni ori rere, ti kò ni iwà, iwà rẹ ni yio ba ori rẹ̀ jẹ́ fihàn pé Jimmy Savile fi iwà àbùkù ba iṣẹ́ rere ti ó ṣe jẹ Ìṣẹ̀lẹ̀ Jimmy Savile kò ṣe àjòjì ni ilẹ̀ Yorùbá Ni ayé àtijọ́, àwọn Ọba tàbi Olóyè miran ma ńlo ipò wọn lati ṣe iṣẹ ibi – bi ki wọn gbé ẹsẹ̀ lé ìyàwó ará ilú, fi ipá gba oko tàbi ilẹ̀ ará ilú lai si ẹni ti ó lè mú wọn ṣùgbọ́n láyé òde òni, Ọba tàbi Olóyè ti ó bá hu iwà burúkú wọnyi, yio tẹ́ Olóyè Yorùbá ti ó bá fi ipò tàbi ọlá hu iwà ikà ni ayé igbàlódé yi, kò ri ibi pamọ́ si, nítorí àṣiri á tú ninú iwé-ìròyìn, ẹ̀rọ-asọ̀rọ̀-mágbèsi, ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán àti lori ayélujára Ki ṣe ará ilú nikan ló lè ṣe ìdájọ́ fún Ọba ti ó bá hu iwà ikà nípa ri-rọ̀ lóyè, gbogbo àgbáyé ni yio ṣe idájọ́ fun, irú Ọlọ́rọ̀ bẹ́ẹ̀ yio tun fi ojú ba ilé-ẹjọ́ Fún àpẹrẹ Ọba Adébùkọ́lá Alli – Alọ́wá ti Ìlọ́wá ti obinrin Agùnbánirọ̀ fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ipá ni àṣepọ̀ àti Déji Àkúrẹ́ ti wọn rọ̀ lóyè nítorí iwa àbùkù – Oluwadare Adeṣina Gbogbo Ẹranko kó ara jọ lati gbèrò lórí àlébù tí wọ́n rí lára ìyàwó wọn Ajá, Àmọ̀tẹ́kùn, Ẹkùn, Kìnìún, Ọ̀bọ, Akátá, Ológbò, Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, Ìjàpá àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ajá ní ìyàwó òhun nṣe àgbèrè, Ẹkùn ní ìyàwó òhun nṣe àfojúdi, Ológbò ní ìyàwó òhun njale, Ọ̀bọ ní ìyàwó òhun lèjàjù àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Àwọn Ẹranko yókù ṣe àkíyèsí wípé, Ìjàpá kàn mi orí ni lai sọ nkankan ju un! Kìnìún wa bèrè lọ́wọ́ Ìjàpá wípé ṣe Yáníbo kòní àlébù ni Àjàpá dìde ó wá fọhùn wípé gbogbo àlébù ti gbogbo wọn sọ nípa ìyàwó wọn kéré lára ti ìyàwó ohun nítorí Yáníbo kò ní ìtìjú Ẹni ti kó ni ìtìjú a jalè, a purọ́, a ṣe àgbèrè, a ṣe àfojúdi àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ni Ìlúọba, bi Òṣèlú bá ṣe ohun ìtìjú bi àgbèrè, jalè, gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bi wọn bá ka mọ tàbí kó rò wípé aṣírí fẹ́ tú, á gbé ìwé sílẹ̀ pé òhun kò ṣe mọ nítorí ki ipò òhun má ba di ìdájọ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n apàniyàn, olè, alágbèrè àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, pọ nínú Òṣèlú Nàíjíríà nítorí wọn kò ni ìtìjú Ipò Òṣèlú tiwọn fún wọn láyè lati ni àlébù àti lati tẹ ìdájọ́ mọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Yorùbá tó ni Àìnítìjú lọba gbogbo Àlébù gba èrò lati ri wípé ará ìlú dìbò fún Afínjú Òṣèlú kí wọ́n lè ṣe àtúnṣe nkan tí aláìnítìjú Òṣèlú ti bàjẹ́ Ninú Ẹ̀yà mẹrin-din-logoji orilẹ̀ èdè Nàíjíríà, ẹ̀yà mẹ́fà ni o wa ni ìpínlẹ̀ Yorùbá lápapọ̀ Àwọn ẹ̀yà wọnyi ni Èkó – ti olú ilú rẹ jẹ Ìkẹjà, Èkiti – ti olú ilú rẹ jẹ Adó-Èkiti, Ò̀gùn – ti olú ilú rẹ jẹ Abẹ́òkúta, Ondo – ti olú ilú rẹ jẹ Àkúrẹ́, Ọ̀ṣun – ti olú ilú rẹ jẹ Òṣogbo àti Ọyọ – ti olú ilú rẹ jẹ Ìbàdàn ọ̀pọ̀ ara Ọ̀ṣun dibò àti bójú tó ibò wọn Ni Òkè-Òkun, bi enia ba ni ẹjọ́ ni ilé-ẹjọ́, tàbi ó ti ṣe ẹ̀wọ̀n ri, tàbi hùwà àbùkù miran, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè gbé àpóti ibò ṣùgbọ́n, ti kò bá ni itiju, ti ó gbé àpóti ibò, ọ̀pọ̀ àwọn èrò ilú kò ni dibò fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ Eyi kò ri béè ni orilẹ-èdè Nàíjíríà, nítorí, ẹlẹ́wòn, eleru, olè, apànìyàn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, ti ó di olówó ojiji ló ńgbé àpóti ibò nítorí wọn mọ̀ pé àwọn lè fi èrú dé ipò Àwọn èrò ẹ̀yà Ọ̀ṣun fi òwe Yorùbá ti o ni Ọ̀pọ̀ ni eṣú fi ńya igi oko hàn ni idibò ti ó kọjá ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹsan, oṣù kẹjọ, ọdún Ẹgbàálemẹ́rìnlá, wọn kò bẹ̀rù bi Ìjọba àpapọ̀ Nàíjíríà ti kó Ológun àti ohun ijà ti àwọn ará ilú lati da ẹ̀rù bà wọn Wọn tú jáde lati fi ọ̀pọ̀ dibò àti bójú tó ibò wọn lati gbé Góminà Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹ́gbẹ́ṣọlá padà Àgbá ti ó kún fún ohun ti ó wúlò bi epo-rọ̀bì, epo-pupa, epo-òróró, epo-òyìnbó, ọ̀dà àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ki pariwo Àgbá òfìfo, kò ni nkan ninú tàbi o ni nkan díẹ̀, irú àgbá yi bi o ti wù ki ó lẹ́wà tó, ni ariwo rẹ máa ńpọ̀ ti wọn ba yi lóri afárá tàbi ori titi ọlọ́dà Àgbá òfìfo ti ó lẹ́wà Àgbá òfìfo ni àwọn ti ó wà ni ilú òyìnbó ti ó jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati wá ṣe àṣehàn ti wọn bá ti àjò bọ, ohun ti wọn kò tó wọn a pariwo pé àwọn jù bẹ́ẹ̀ lọ Ni tòótọ́, ìyàtọ̀ ilú-òyìnbó si ilẹ̀ Yorùbá ni pé, àti ọlọ́rọ̀ àti aláìní ló ni ohun amáyé-dẹrùn bi omi, iná mọ̀nà-mọ́ná, titi ọlọ́dà, ilé-iwé gidi, igboro ti ó mọ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Àwọn Òṣèlú kò kọjá òfin, bẹni irònú wọn ki ṣe ki á di Òṣèlú lati kó owó ilú jẹ Ni ayé àtijọ́ ni ilẹ̀ Yorùbá, owó kọ́ ni wọn fi ńmọ ẹni gidi, àpọ́nlé wà fún àgbà, ẹni ti ó bá kàwé, olootọ enia, ẹni tó tẹpá mọ́ṣẹ́, akin-kanjú àti ẹni ti ó ni òye Ni ayé òde òni, àgbá òfìfo ti pọ ninú ará ilú, àwọn Òṣèlú àti àwọn òṣiṣẹ́ ijọba Bi wọn bá ti ri owó ni ọ̀nà èrú, wọn a lọ si òkè-òkun lati ṣe àṣehàn si àwọn ti wọn bá lọhun lati yangàn pẹ̀lú ogún ilé ti wọn kọ́ lai yáwó, ọkọ̀ mẹwa ti wọn ni, ọmọ-ọ̀dọ̀ ti wọn ni àti ayé ijẹkújẹ ti wọn ńjẹ ni ilé Wọn á ni àwọn kò lè gbé ilú-òyìnbó, ṣùgbọ́n bi àìsàn bá dé, wọn á mọ ọ̀nà òkè-òkun fún iwòsàn àti lati jẹ ìgbádùn ohun amáyé-derùn miran ti wọn ti fi èrú bàjẹ́ ni ilú tiwọn Bi àgbá ti ó ni ohun ti ó wúlò ninú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹni gidi tó ṣe àṣe yọri ki pariwo Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni Àgbá òfìfo ló ńdún woro-woro, bá ẹni-kẹ́ni ti ó bá ńṣe àṣehàn tàbi gbéraga wi pé ki wọn yé pariwo ẹnu Àwọn èlò ọbẹ̀ Yorùbá, ẹni ti ó bá mọ ọbẹ̀ se, yio mọ èlò ọbẹ̀ ti ohun yio ra àti bi yio ti se, ṣùgbọ́n ẹni ti kò mọ ọbẹ̀ se, lè lo owó ai mọye lati se ọbẹ̀, ki ọbẹ̀ rẹ má dùn Fún àwọn ti ó ńgbé ni Òkè-Òkun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èlò yi ni a lè ri rà ni àyiká Ẹṣe àyẹ̀wò èlòọbẹ̀ àti pípè rẹ ni ojú ewé yi Ọkùnrin kan wa láyé àtijọ́, Ògbójú-ọdẹ ni, ṣùgbọ́n bi ó ti pa ẹran tó, kò fi dá nkan ṣe Ọ̀pọ̀ igbà, ki ri ẹran ti ó bá pa tà, o ma ńpin fún ará ilú ni Nígbàtí kò ri ẹran pa mọ́, ó di o Ọdẹ-apẹyẹ Ni ọjọ kan, ògbójú-ọde yi ri ẹyẹ Òfú kan, ṣùgbọ́n ọta ibọn kan ṣoṣo ló kù ninú ibọn rẹ Gẹgẹbi Ògbójú-ọdẹ, o yin ẹyẹ Òfú ni ibọn, ọta kan ṣoṣo yi si báa Ó bá wọ igbó lọ lati gbé ẹyẹ ti ó pa, lai mọ̀ pé ẹyẹ yi kò kú Ó ṣe akitiyan lati ri ẹyẹ́ yi mu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ si wọ igbó lọ titi ó fi ṣi ọ̀nà dé ilẹ̀ àwọn Ará-Ọ̀run – àwọn ti wọn ńpè ni Abàmi-ẹ̀dá Inu bi àwọn Ará-Ọ̀run nítorí Ògbójú-ọdẹ yi jálu ipàdé wọn Wọn gbamú, wọn ni ki ó ṣe àlàyé bi ó ṣe dé ilẹ̀ wọn, ki àwọn tó pá Ọdẹ ṣe àlàyé ohun ti ojú rẹ ti ri nípa iṣẹ́ àti jẹ àti gbogbo ohun ti ojú rẹ ti ri lẹ́nu iṣẹ́ ọde Àwọn Ará-Ọ̀run ṣe àánú rẹ, wọn bèrè pé ṣe ó lè dá ẹmu, ó ni ohun lè dá ẹmu diẹ-diẹ Wọn gbaa ni iyànjú pé ki o maṣe fi ojú di iṣẹ kankan, nítorí naa, ki ó bẹ̀rẹ̀ si dá ẹmu fún àwọn Wọn ṣe ikilọ pe, bi ó bá ti gbé ẹmu wá, kò gbọdọ̀ wo bi àwọn ti ńmu ẹmu, ki ó kàn gbé ẹmu silẹ ki o si yi padà lai wo ẹ̀hin Bi ó bá rú òfin yi, àwọn yio pa Ọdẹ bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún ara orun Bi ó bá gbé ẹmu dé, a bẹ̀rẹ̀ si kọrin lati jẹ ki àwọn Ará-Ọ̀run mọ̀ pé ohun ti dé, lẹhin èyi á gbé ẹmu silẹ á yi padà lai wo ẹ̀hin gẹgẹ bi ikilọ Ará-Ọ̀run Ni ọjọ́ keji, á bá owó ni idi agbè ti ó fi gbé ẹmu tàná wá Ògbójú-ọdẹ á má kọrin bayi Àyipadà dé fún Ògbójú-ọdẹ ti ó di Ẹlẹ́mu tóó bẹ̀ ti àwọn ará ilú ṣe akiyesi àyipadà yi Yorùbá ni ojú larí, ọ̀rẹ́ ò dénú Àjàpá, ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, sọ ara rẹ̀ di ọrẹ kòrí-kòsùn pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ nítorí àti mọ idi ọrọ̀ rẹ Laipẹ, àrùn Ṣọ̀pọ̀ná bo Ògbójú-ọdẹ, eleyi dá iṣẹ́ àti gbé ẹmu fún àwọn Ará-Ọ̀run dúró Gẹgẹbi ọ̀rẹ́, ó bẹ Àjàpá pé ki ó bá ohun bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún àwọn Ará-Ọ̀run Ó ṣe ikilọ fún Àjàpá, bi ikilọ ti àwọn Ará-Ọ̀run fi silẹ̀ Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ, ni ọjọ́ keji ti ó ri owó rẹpẹtẹ ti àwọn Ará-Ọ̀run kó si idi agbè ẹmu àná, ó pinu lati mọ idi abájọ Àjàpá, fi ara pamọ́ si igbó lati wo bi àwọn Ará-Ọ̀run ti ńmu ẹmu Ohun ti ó ri yàá lẹ́nu, ó ri Ori, Ẹsẹ̀, Ojú, Apá àti àwọn ẹ̀yà ara miran ti wọn dá dúró, ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si mu ẹmu Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si fi àwọn Ará-Ọ̀run ṣe yẹ̀yẹ́ Nígbàtí wọn gbọ, wọ́n le lati pá ṣùgbọ́n, Àjàpá, sá àsálà fún ẹmi rẹ, ó kó wọ inú ihò, wọn kò ri pa Ògbójú-ọdẹ reti titi ki Àjàpá kó owó ẹmu dé Nígbàtí Àjàpá dé, ó gbé irọ́ kalẹ̀ pé olè dá ohun lọ́nà, wọn gba gbogbo owó ẹmu lọ ni ohun ṣe pẹ́ Ara Ògbójú-ọdẹ ya, ó gbé ẹmu lọ fún ara-orun gẹgẹbi iṣe rẹ tẹ́lẹ̀ lai mọ iwà àkóbá ti Àjàpá, ti hù silẹ̀ Àwọn Ará-Ọ̀run wọ ijàkàdi pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ, nítorí ó rú òfin ikilọ ti wọn fun Nítorí imọ̀ ti ó ni lẹ́nu iṣẹ Ọdẹ, Ará-Ọ̀run ko ri Ògbójú-ọdẹ pa Lẹhin ijàkàdi, ó ṣe àlàyé pé ara ohun ni kò yá, ó fi àpá han, pé nítorí eyi ni ohun ṣe bẹ ọ̀rẹ́ ohun Àjàpá, ki ó bá ohun gbé ẹmu lọ fún wọn Wọn ṣe àlàyé ohun ti Àjàpá ti ó pè ni ọ̀rẹ́ rẹ ṣe fún wọn Ará-Ọ̀run dariji Ògbójú-ọdẹ pẹ̀lú ikilọ pé ki o maṣe gbára lé ọ̀rẹ́ Wọn ni ọpọlọpọ ọrẹ o ṣe fi okùn ọlà han, nítorí ọ̀pọ̀ ọ̀tá ló ńṣe bi ọ̀rẹ́ nítorí àti jẹ Orúkọ ẹni ni ìfihàn ẹni, orúkọ Yorùbá fi àṣà, iṣẹ́ àti Òriṣà idile hàn tàbi àtẹsẹ̀bi ọmọ Yorùbá gbàgbọ́ ninú Ọlọrun ki ẹ̀sin igbàgbọ́ àti imọ̀le tó dé Ifá jẹ́ ẹ̀sin Yorùbá, nítorí Ifá ni wọn fi ń��e iwadi lọ́dọ̀ Ọlọrun ki Yorùbá tó dá wọ́ lé ohunkohun Yorùbá gbàgbọ́ ninú àwọn iránṣẹ́ Ọlọrun ti a mọ̀ si Òriṣà Àwọn Òriṣà Yorùbá pọ̀ ṣùgbọ́n pàtàkì lára àwọn Òriṣà ni Ògún, Ṣàngó, Ọya, Yemọja, Oṣó, Ọ̀ṣun, Olokun, Ṣọ̀pọ̀ná, Èṣù àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Àwọn orúkọ ti ó fi ẹ̀sin àwọn Òriṣà wọnyi hàn ti ńparẹ́ nítorí àwọn ẹlẹsin igbàlódé ti fi Ọlọrun dipò orúkọ ti ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ifá, Ògún, Èṣù àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ wọnyi Ni ayé àtijọ́, wọn ma ńfi obinrin fún ọkọ ni, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, obinrin á mú̀ àfẹ́sọ́nà lati fi hàn òbi, nítorí Yorùbá gba ọmọ obinrin ni àyè lati lọ si ilé-iwé, tàbi kọ́ iṣẹ́-ọwọ́, àti lati ṣe òwò Èyi jẹ ki obinrin kúrò lọ́dọ̀ obi wọn Bi obinrin bá ti dàgbà tó bi ọdún méjì-din-logun, ti ó tó wọ ilé-ọkọ, àwọn òbi yio ma ran léti pé, ó ti tó mú ọkọ wálé Ẹni ti obinrin mọ̀ pé òhun kò lè fẹ́, bi àfojúdi ni lati fi irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ han òbi Bi obinrin ti ó ti dàgbà tó lati wọ ilé ọkọ bá mú àfẹ́sọ́nà wá han òbi, wọn yio fi òwe Yorùbá ti ó ni A ki mọ́ ọkọ ọmọ, ki a tún mọ àlè rẹ ṣe iwadi pé, ṣe ó da lójú pé òhun yio fẹ ọkùnrin ti ó mú wá Òwe yi tún wúlò lati fi ṣe ikilọ nigbà igbéyàwó ibilẹ̀ fún obinrin pé kò lè mú ọkùnrin miràn wá lẹhin igbéyàwó À ńlo ọ̀rọ̀ yi fún àwọn Ayáni-lówó ki ba jẹ Ilé-owó tàbi àwọn Ayáni-lówó yókù Ọ̀pọ̀ ìgbà, Ayáni-lówó ló ndá orin nípa oye èlé ti wọn lè fi lé owó ti Onígbèsè ya Ni ilẹ̀ Yorùbá ohun ti a lè fi ṣe àpèjúwe Ilé-iṣẹ́ Ayáni-lówó ni bi Ọba bá fún ni nilẹ̀ lati fi dá oko, Ọba lè ni ki irú ẹni bẹ kó idá-mẹrin, tàbi idá-marun irè oko náà wá ni igbà ìkórè Àwọn miran tún ma ńyá owó lọwọ Olówó-èlé Ẹ̀yà Yorùbá ti a mọ si Ìjẹ̀ṣà ma ńṣe òwò aṣọ àti wúrà tità lati ilú dé ilú àti agbègbè dé agbègbè Bi wọn ba ti ta àwin fún onibara, bi ọjọ́ bá pé, Ìjẹ̀ṣà á ji lọ si ilé Onígbèsè lati gba owó ọjà, á ni Òṣó máà ló gbowó mi loni nítorí eyi ni wọn fi npe Ìjẹ̀ṣà ni Òṣó máà ló Ike-ìyáwó kò wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n àwọn enia ma ńyá owó lọ́wọ́ ẹbi, ọ̀rẹ́, ẹgbẹ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, lati sin òkú, sán owó ilé iwé ọmọ, ṣòwò àti fún ọ̀pọ̀ idi miran Èlé owó irú eyi kò pọ̀ tó ti èlé ori Ike-ìyáwó, nigbà miran kò ki ni èlé Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ ti ó niẸni sanwó Onífèrè ló ndá orin Ayáni-lówó ló ńdá orin nípa di dari èlé ori owó Ike-ìyáwó Ẹni ti o fi owó pamọ́ ki ri èlé gbà tó èlé ti ó wà lori owò Ike-ìyáwó Nibiti èlé owó ipamọ́ bá jẹ́ idá-ọgọrun, èlé owó ori ike-ìyàwó lè tó idá-marun tàbi jù bẹ́ẹ̀ lọ Bi owó bá ti tó san, ọ̀pọ̀ Ayáni-lówó lè fi ipá gba owó irú bẹ́ẹ̀ Bi wọn kò ti ẹ̀ fi ipá gba irú owó bẹ́ẹ̀, èlé ori owó yi á sọ ẹni ti ó yá owó di Onigbèsè rẹpẹtẹ Ike-ìyáwó ni iwúlò fún ẹni ti ó bá lè kó ara rẹ ni ijánu lati dá owó padà nígbàtí ó bá yẹ Ike-ìyáwó dùn lati nọ́ ju owó gidi lọ nítorí eyi, fún ẹni ti kò bá mọ owó ṣirò tàbi ṣọ́ra, á sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di òtòṣi, nígbàtí èlé bá gun ori èlé Onigbèsè pàdánù òmìnira Ìmọ́tótó borí àrùn mọlẹ̀, bọ́yẹ́ ti ḿborí ooru Àrùn ìwọ̀sí tinú ẹ̀gbin là wá Iná ni ḿborí aṣọ ẹlẹ́gbin Ni ayé àtijọ́ tàbi, lati bi agogo marun idaji ni ìmọ́tótó ti bẹ̀rẹ̀, nípa gbigbá inú àti àyiká ilé Lẹhin eyi, àwọn àgbàlagbà á ṣe itọ́jú ara, wọn o si bójú tó bi àwọn ọmọ ilé-iwé yio ti ji, wẹ̀, múra, jẹun àti palẹ̀mọ́ àti kúrò ni ilé lọ si ilé-iwé àti ki àwọn àgbàlagbà lọ si ibi iṣẹ́ òòjọ́ Mọ́inmọ́in Ọ̀lẹ̀lẹ̀ Eléwé Pàǹtí ni àtijọ́ wúlò fún ajílẹ̀ nítorí ara oúnjẹ ni Ewé ni wọn fi ńpọ́n oúnjẹ tàbi ki wọn bu oúnjẹ sinú abọ́ àlò-tún-lò, omi wa ninú àmù, ṣùgbọ́n láyé òde òni, ike aláyọ́ ni wọn fi ńbu oúnjẹ, wọn a si mu omi ninú àpò ọ̀rá Ike àti ọ̀rá ki kẹ̀, ó si léwu fún ẹja odòàti ẹranko lati gbé mi, ó tún léwu fún àyìká Àwọn ọ̀rá àti ike wọnyi pẹ̀lú nkan ti ó dá kún pàǹtí Ìmọ́tótó jinà si àwọn ara ilú ńlá, pàtàkì, ilú Èkó nibiti ọpọ òṣiṣẹ́ ti ji jade lọ si ibi iṣẹ́ ki agogo marun idaji tó lù, bẹni wọn kò ni wọlé titi di agogo mẹwa alẹ́ nítorí sún-kẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ̀ Eyi kò lè jẹ ki wọn ri àyè tọ́jú inú ilé, àyiká tàbi ara Ìjọba tún dá kún ẹ̀gbin ti ó gba ilú kan nítorí ai pèsè àyè àti itọ́jú fún pàǹtí Eleyi ńjẹ́ ki ará ilú kó ohun ẹ́gbin si ibikibi, bi oju-àgbàrá, ẹ̀bá-ọ̀nà, ori titi, inú odò àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Kikó ohun ẹ̀gbin di ojú-àgbàrá ńfa adágún omi ti ó ńfa ẹ̀fọn, ikún omi àti àrùn lati ara kòkòrò ti pàǹtí fa Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni Ìmọ́tótó borí àrùn mọ́lẹ̀, bi ọyẹ́ ti ḿborí ooru àti orin Ìmọ́tótó ti wọn fi ńkọ́ àwon ọmọ ilé-iwé alakọbẹrẹ ṣe iranti à ti wá nkan ṣe si pàǹtí ti ó gba ilú kan Ògòngò jẹ ẹiyẹ ti ó tóbi jù ninú gbogbo ẹiyẹ, ẹyin rẹ ló tún tóbi jù Ọrùn àti ẹsẹ̀ rẹ ti ó gún jẹ́ ki ó ga ju gbogbo ẹiyẹ yoku Ògòngò ló lè sáré ju gbogbo eiye lọ lóri ilẹ̀ Eyi ló jẹ́ ki Yorùbá pe Ògòngò ni Ọba Ẹiyẹ Ọpọlọpọ ẹiyẹ bi Ògòngò kò wọ́pọ̀ mọ́ nítorí bi ilú ti nfẹ si bẹni àwọn eiye wọnyi nparẹ́, a fi bi èniyàn bá lọ si Ilé-ikẹransi lati ri wọn Àwọn onírúurú ẹiyẹ ló wà ni ilẹ̀ Yorùbá, àwọn eyi ti ó wọ́pọ̀ ni ilú tàbi ilé ni, Adiẹ, Pẹ́pẹ́yẹ, Ẹyẹlé, Awó, Ayékòótó́ àti Ọ̀kín Àwọn ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ninú igbó ṣùgbọ́n ti ará ilú mọ̀ ni Àṣá, Ìdì, Òwìwí, Àkàlàmàgbò àti Lekeleke Àwọ̀ oriṣirisi ni ẹiyẹ ni, irú ẹiyẹ kan lè ni àwọ̀ dúdú bi aró, kó́ tun ni pupa tàbi funfun, ṣùgbọ́n orin Yorùbá ni ojú ewé yi fi àwọ̀ ti ó wọ́pọ̀ lára àwọn ẹiyẹ miran hàn Fún àpẹrẹ, Lekeleke funfun bi ẹfun, Agbe dúdú bi aró, bẹni Àlùkò pọn bi osùn Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán àti pipè orúkọ di ẹ ninú àwon ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, ni ojú ewé yi Wúrà jẹ ikan ninú ohun àlùmọ́ni iyebiye, pàtàkì fún ohun ẹ̀ṣọ́ Ẹwà Wúrà ki hàn, titi di ìgbà ti wọn bá yọ gbogbo ẹ̀gbin rẹ̀ kúrò pẹ̀lú iná tó gbóná rara Àwòrán ti ó wà ni ojú ewé yi fihàn pé bi Wúrà bá ti pọ̀ tó lára ohun ẹ̀sọ́ ló ṣe má wọn tó, ki ṣé bi ohun ẹ̀ṣọ́ bá ti dán tó tàbi tóbi Fún àpẹrẹ, àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà kini tóbi, ó si dán ju àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà keji, ṣùgbọ́n ohun ẹ̀sọ́ Wúrà ninú aworan keji wọn ju ohun eso Wúrà kini ni ìlọ́po mẹwa Ìyàtọ̀ ti ó wà ni Wúrà gidi àti àfarawé ni pé, Wúrà gidi ṣe é tà fún owó iyebiye lẹhin ti èniyàn ti lo o, kò lè bàjẹ, bi ó bá kán, ó ṣe túnṣe, ṣùgbọ́n àfarawé kò bá ara ẹlòmiràn mu, bi ó bá kán, kò ṣe é túnse, kò ki léwó Gẹ́gẹ́bi òwe Yorùbá ti ó sọ pé Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà, bẹni ki ṣe gbogbo èniyàn ti wọ̀n pè ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ló tó bi àwọn èniyàn ti rò Ọ̀pọ̀ irú àwọn wọnyi, jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati ṣe àṣe hàn, òmiràn ja olè, gbọ́mọgbọ́mọ àti onirúurú iṣẹ́ ibi yoku Gbogbo ohun ti wọn fi ọ̀nà èrú kó jọ wọnyi kò tó nkankan lára ọrọ̀ ti ẹlòmiràn ti ó ni iwà-irẹ̀lẹ̀ ni Fún àpẹrẹ, owó ti àwọn Òṣèlú àti Òṣiṣẹ́-Ìjọba ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú fi èrú kó jọ, ti wọn nkó wá si Òkè-òkun tàbi fi mú àwọn èniyàn wọn lẹ́rú, kò tó ọrọ̀ ti ọmọdé ti ó ni ẹ̀bun-Ọlọrun ni Òkè-òkun ni A lè fi òwe Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà gba ẹnikẹ́ni ni iyànjú pé ki wọn ma ṣe àfarawé, tàbi kánjú lati kó ọrọ̀ jọ Àfarawé léwu, nítorí ki ṣe gbogbo ohun ti èniyàn ri ló mọ idi rẹ̀ Babá re lé ò Ilé ló lọ́ tarà-rà Bàbá re lé ò Ilé ló lọ́ tarà-rà Ilé ò, ilé, Ilé ò, ilé Babá re lé ò Ilé ló lọ́ tarà-rà Ni Àṣà Yorùbá, ọmọdé ló nkú, àgbà ki kú, àgbà ma nrelé ni Ọ̀fọ̀ ni ikú ọmọdé jẹ́, ijó àti ilú ni wọn fi nṣe ìsìnku àgbà lati sín dé ilé ikẹhin Ìròyìn ikú Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí kàn lẹhin ikú rẹ ni ọjọ́ kẹsan, oṣù kẹjọ,ọdún Ẹgbàálemẹ̀rinlá A bi ni ilú Ìkọ̀lé-Èkìtì ni ọdún marun-le-lọgọrin sẹhin Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n, ọmọdé àti àgbà ilú lati onírúurú iṣẹ́àti àwọn èniyàn pàtàkì ni ilé-lóko péjọ ni ọjọ kọkàn-din-logun, oṣù kẹsan, ọdún Ẹgbàálemẹ̀rinlá lati ṣe ìsìnku rẹ Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ pé Ẹni ti kò bá mọ ìtàn ara rẹ, yio dahun si orúkọ tí kò jẹ́ Ki awọn bi Olóògbé tó bẹ̀rẹ̀ si kọ Ìtàn Yorùbá àti ilẹ́ Aláwọ̀-dúdú silẹ̀, àwọn Aláwọ̀-funfun kò rò pé Aláwọ̀-dúdú ni Ìtàn nítorí wọn kò kọ silẹ̀, wọn nsọ Ìtàn lati ẹnu-dé-ẹnu ni Nítorí eyi, ohun ti ó wu Aláwọ̀-funfun ni wọn nkọ Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí, kọ́ ẹ̀kọ́, ó si gboyè rẹpẹtẹ lori Ìtàn, pàtàkì lati jẹ́ ki Yorùbá mọ ìtàn ara wọn Ó lo imọ̀ yi lati kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iwé itan, ikan lára iwé wọnyi ni Ìtàn àti Ogun jijà Yorùbá Ó tún kọ nípa Ìgbési-ayé Olóògbé Olóri àwọn Alufaa Àjàyí Crowther àti Onidajọ Káyọ̀dé Ẹ̀ṣọ́ Yorùbá pa òwe pé Àgbà ki wà lọ́jà, ki ori ọmọ titun wọ, Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí ni Igbá-keji Ilé-ẹ̀kọ́ Giga, Èkó kẹta Nítorí ìfẹ́ ti ó ni si ìdàgbà sókè Ilé-ẹ̀kọ́ Giga, ìtàn àti ìpamọ́ ohun-ìtàn, ó kọ iwé si Olóri Òṣèlú Nàíjíríà, nigbà Ìporúkọdà lójiji lati Ilé-ẹ̀kọ́ Giga Èkó si orúkọ Olóògbé MKO Abiọ́lá – ti gbogbo ilú dibò fún lati ṣe Olóri Òṣèlú, ṣùgbọ́n àwọn Ìjọba Ológun kò jẹ́ kó dé ipó yi Olóri Òṣèlú Nàíjíríà yi ọkàn padà lati ma yi orúkọ Ilé-ẹ̀kọ Giga yi padà lojiji nítorí ọ̀wọ̀ ti ó ni fún Olóògbé Igbá-keji Ilé-ẹ̀kọ́ Giga Èkó, lọ́wọ́lọ́wọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Adisa Bello juwe pe, àsikò ti Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí jẹ́ Igbá-keji Ilé-ẹ̀kọ́ Giga Èkó kẹta ni ọdún keji-le-lógóji titi di ọdún kẹrin-din-lógóji ni wọn kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ ohun amáyé-dẹrùn fún Akẹkọ ti ó wà titi di ọjọ́ òni àti ibẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ àwọn ti ó kàwé jáde Ni igbà ayéOlóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí, pẹlu idùnú, ẹbi, ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀, àti àwọn èniyàn pàtàkì lati ilé àti Òkè-okun péjọ lati ṣe ìrántíọjọ́-ìbí karun-le-ọgọrin Wọn gbé iwé ti wọn kọ nípa igbési-ayé rẹ si ìta, bẹni wọn fi hàn pé ó jẹ́ Ọmọluwabi ti wọn fẹ́ràn Ayé yẹẹ́ Gbogbo Olùkọ̀wé Àṣà àti èdè Yorùbá lóri ayélujára gbàdúrà ki ọ̀run yẹ àti ki iṣẹ́ ti óṣe silẹ̀ má bàjẹ́ lágbára Èdùmàrè. Àṣẹ Ódìgbóṣe, sùn re o Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ni, ìlàjú lóri ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán àti ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-mágbèsi gbàlà lọ́wọ́ ikú igbẹ́-gburu, nípa ìmọ̀ Omi Oni-yọ lati dipò omi ara Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ bi Àbíkú ti din-ku ni orilẹ̀ èdè Nàíjíríà, nítorí eyi orúkọ Àbíkú din-kù Ikú ọmọ ti kò ti pé ọdún marun ni ọdún mẹrinlélógún sẹhin jẹ́ Igbalémẹ́tàlá Ikú ọmọ ti kò ti pé ọdún marun ni ọdún keji sẹhin ti din-kù si Mẹrin-lé-lọgọfa Ìgbàgbọ́ Yorùbá yàtọ̀ si ohun ti àwọn Ẹlẹko-Ijinlẹ fi hàn ni ayé òde òni Ni igbà àtijọ́, bi ìyàwó bá bi ọmọ, ti ó kú ni ikókó tàbi ki ó tó gba àbúrò, ọmọ ti wọn bá bi lẹhin rẹ ni wọn ma fún ni orúkọ Àbíkú pàtàkì ti ó bá tó bi méjì, mẹta ki ọmọ tó dúró Yorùbá gbàgbọ́ ninú àpadà-wáyé, ni igbà miran, wọn á fi ibinú fi àmin, bi ki wọn kọ ilà si ara ọmọ ti ó kú tàbi gé lára ẹ̀yà ara ọmọ yi lati mọ bóyá yio padà wá Bi ìyá ti ó bi Àbíkú bá bímọ lẹhin ikú ọmọ ti wọn fi àpá si lára, àpá yi ni wọn ma kọ́kọ́ wò lára ọmọ titun Bi wọn bá ri àpá yi, wọn o sọ ọmọ naa ni orúkọ Àbíkú Orúkọ àbùkù ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ Àbíkú – ó lè jẹ́ orúkọ ẹranko, orúkọ ti ó fi ìbẹ̀rù hàn, tàbi orúkọ fún ìmọràn Àbíkú jẹ́ ikú ọmọdé àti ìkókó titi dé ọmọ ọdún marun Ẹkọ-Ijinlẹ fi hàn pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikú ọmọdé ti Yorùbá mọ̀ si Àbíkú yi ti ìpasẹ̀ wọnyi wá àrùn tó ṣe-dádúró, oúnjẹ-àìtó, omi-ẹlẹgbin, ilé-iwòsàn ti kò pé tàbi ai si ilé-iwòsàn, àrùn àti àjàkálẹ̀-àrùn, ọmọ ti ó ni iwọn-kékeré nigbà ìkókó Òwe Yorùbá ti o ni Àbíkú sọ Olóògùn di èké fi ìgbàgbọ́ Yorùbá hàn pé, kò si oògùn ti ó lè dá Àbíkú dúró Ìmọ̀ Ijinlẹ fi hàn pe ki ṣe gbogbo ọmọ ti ó kú, ni ó yẹ ki ó kú, nítorí lati igbà ti àtúnṣe àwọn ohun ti ó nfa ikú ọmọdé yi ti wà, Àbíkú din-kù – nípa ìpèsè omi ti ó mọ́, ilé-ìwòsàn ọmọdé, ilà-lóye àwọn obinrin nípa ìtọ́jú aboyún àti ọmọdé Òrùlé wà lára ohun ini pàtàkì ti ó yẹ ki èniyàn ni, ṣùgbọ́n èniyàn kò lè sun yàrá méjì pọ̀ lẹ́ẹ̀kan Ki ṣe bi èniyàn bá fi owó ara rẹ̀ kọ́ ilé ni ìbẹ̀rẹ̀ ilé gbigbé Bàbá á pèsè òrùlé fún aya àti ọmọ, ki ba jẹ ilé ẹbi, abà oko, ihò inú àpáta, ilé-àyágbé tàbi kọ́ ilé fún wọn Ni ayé òde oni, ilé ṣi jẹ ohun pàtàkì fún èniyàn, ṣùgbọ́n á ṣe akiyesi pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ Yorùbá, kò ránti ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé Ọ̀kọ́lé, kò lè mu ràjò mọ́ Ọ̀pọ̀ nkọ́ ilé àìmọye ti èniyàn ò gbé, lai ronú pé, bi àwọn bá ràjò, wọn ò lè gbé ikan ninú ilé yi dáni Ọ̀pọ̀ nkọ́ ilé fún àwọn ọmọ – fún àpẹrẹ, ẹni ti ó kọ ilé marun nítorí ohun bi ọmọ marun si ilú ti wọn ngbé tàbi bi ọmọ si Ò̀we Yorùbá sọ pé Ọ̀nà ló jin, ẹru ni Baba Ẹ jẹ́ ki á fi òwe yi ṣe iranti pé, ayé ti lu jára, ọmọ, ẹbi àti ará kò gbé pọ̀ mọ́ bi igbà ayé-àgbẹ̀ Bi wọn bá ti ẹ̀ gbé ilú kan naa, ìṣòro ni ki ọmọ bá Bàbá àti Ìyá gbé lọ lai-lai Bi ó pẹ́, bi ó yá, ọmọ tó dàgbà, á tẹ si iwájú nítorí bi Bàbá bá kọ́ ilé rẹpẹtẹ si Agége, kò wúlò fún ọmọ ti o nṣiṣẹ ni Ìbàdàn, Àkúrẹ́ tàbi Òkè-òkun Bi Bàbá ti ó kọ ilé rẹpẹtẹ bá fẹ́ lọ ki àwọn ọmọ, ẹbi tàbi ọ̀rẹ́ ni ilú miran, ìṣòro ni ki ó gbé ikan ninú ilé rẹpẹtẹ yi dáni Ọ̀pọ̀ oníjìbìtì, Òṣèlú, Oníṣẹ́-Ìjọba ti ó ni ojúkòkòrò ló nkó owó ilé lọ sita lati lọ ra ilé si Òkè-Òkun lai gbé ibẹ̀, ju pé ki wọn lo o ni ọjọ melo kan lọ́dún Ìnáwó rẹpẹtẹ ni lati tọ́jú ilé si Òkè-Òkun tàbi ilé ti èniyàn kò gbé , nítorí eyi, ọ̀pọ̀ ilé yi kò bá àwọn ti ó kọ́ ilé tàbi ra ilé kiri yi kalẹ̀ Àwọn Òṣèlu àti Oníṣẹ́ Ìjọba ti ó nja ilú lólè, lati fi owó ti wọn ji pamọ́ nípa ki kọ́ ilé rẹpẹtẹ tàbi ra ilé si Òkè-Òkun ni Orúkọ ọmọ, òbí tàbi orúkọ ti kò ni itumọ, kò lè gbé ilé wọnyi lọ irin àjò tàbi lọ si ọ̀run ti wọn bá kú Ni ayé igbà kan, ọ̀gbẹlẹ̀ wa ni ilú àwọn ẹranko, nítorí ọ̀dá òjò fún igbà pi pẹ́ Ọ̀gbẹlẹ̀ yi fa ìyàn, wọn kò ri omi mu tàbi wẹ̀ Eleyi mú ki gbogbo ẹranko pé jọ lati kó ọgbọ́n pọ̀ bi àwọn yi o ṣe ri omi Kìnìún, Ẹkùn, Erin, Ẹfọ̀n, Àgbọ̀nrín, Òkété, Ehoro, Ọ̀kẹ́rẹ́, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, Àjàpá, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Wọn yan Kìnìún ni Alaga, Ẹkùn jẹ́ igbá keji, Erin jẹ́ Baálẹ̀ Yorùbá sọ pé A sọ̀rọ̀ ẹran ti ó ni ìwo, ìgbín yọjú, Àjàpá binú kúrò ni ìpàdé nítorí wọn kò yan ohun si ipò Alaga Àwọn ẹranko yoku mba ìpàdé lọ, oníkálùkù mú ìmọ̀ràn wá, Àgbọ̀nrín ni ki wọn ṣe ètùtù si Òriṣà-Omi, Òkété ni ki wọn lo ọgbọ́n àti agbára ti Ọlọrun fún wọn, lati gbẹ́ ilẹ̀ jínjìn si ojú odò ti ó ti gbẹ Lẹhin àpérò, wọn gba ìmọ̀ràn ti Òkété múwá, wọn gbẹ́ ojú odò titi wọn fi ri omi Bi iroyin pé wọn ti ri omi ti kàn, Àjàpá ti kò bá wọn ṣiṣẹ́ nítorí ibinú, o gbìmọ̀ bi ohun yi o ti ṣe ẹ̀rù ba àwọn ẹranko yoku ni idi odò, ki ohun lè ri àyè dá pọn omi Ó sọ ara rẹ di Ànjọ̀nú, ó so agbè púpọ̀ pẹ̀lú okùn ti yio fi pọn omi mọ́ gbogbo ara, ó ji lọ idi odò lati dá nikan pọn omi Ó bẹ̀rẹ̀ si kọrin Ìparí ọdún sún mọ́lé, àsikò yi ni àwọn oníjìbìtì ma nbọ́ sita lati ṣe iṣẹ́ ibi, nípa ji ja àwọn ará ilú ti kò bá funra ni olè Ìparí ọdún sún mọ́lé, àsikò yi ni àwọn ẹlẹ́tàn ma nbọ́ sita lati ṣe iṣẹ́ ibi, nípa ji ja àwọn ará ilú ti kò bá funra ni olè Àṣà Yorùbá ni ayé àtijọ́ ni lati gbé àwọn ti ó bá hùwà rere ga, lati yẹ àwọn ti ó bá ṣe iṣẹ́ àṣe yọri si Yorùbá ni Ọmọ ẹ o ṣe àgbàfọ̀, ó kó aṣọ wálé, ẹ ò ri ojú olè bi, ọ̀pọ̀ òbi ki bèrè bi ọmọ wọn ti ri owó mọ nítorí àwọn ẹlẹ̀tàn ori ayélujára àti Òṣèlú nkó ohun ti ki ṣe ti wọn wálé Ẹ̀sìn àti àṣà ayé òde òni ngbe àwọn olè àti oníjìbìtì lárugẹ Nítorí eyi olówó ojiji pọ si láwùjọ laarin ẹni ti ó wà ni ipò giga àti ipò kékeré Iṣẹ́ Ọlọrun àti Òṣèlú ti di ọ̀nà ti èniyàn fi le di olówó lojiji Ọ̀̀pọ̀ ọmọ ilé-iwé giga ti kò ti ilé-ọlọ́rọ̀, tàbi ilé Òṣèlú jade, ti yi si olè jijà lori ayélujára ju pé ki wọn di gun jalè Ni ayé àtijọ́, bi ọdún bá dé, olè jija pẹ̀lú ipá ló wọ́pọ̀, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni iwà ẹ̀tàn ti a mọ̀ si oníjìbìtì pàtàkì ni ori ayélujára ló wọ́pọ̀ Ó ti pẹ ti ẹ̀tàn ori ayélujára ti bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n, irú àsikò yi ni àwọn oníjìbìtì ma nko ọ̀pọ̀ iwe lori ayélujára si ẹgbẹgbẹ̀rún èniyàn ni àgbáyé pẹ̀lú èrò lati jẹ nibi ti wọn kò ṣe si Ẹni ti kò bá funra á jábọ́ si wọn lọwọ, nítorí eyi ẹ ṣọ́ra fún àdàmọdi iwé lati ilé-ifowó-pamọ́ tàbi ọ̀dọ̀ ẹni ti ẹ kò mọ̀ Fún àwọn ti ó wà ni òkè-òkun – America, wọn ni ọjọ́ ti wọn ya si ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bi Ọjọ́ Ọpẹ́ Oúnjẹ pọ rẹpẹtẹ ni àsikò yi pàtàkì ni Ọjọ́ Ọpẹ́, Keresimesi àti ���jọ́ ọdún tuntun Ọ̀pọ̀ á jẹ àjẹ-bi, á tún dà yókù dànù Ni àṣà ibilẹ Yorùbá, ọjọ́ gbogbo ni ọpẹ́ pàtàkì fún àwọn Yorùbá ti ó jẹ́ Onigbàgbọ́ Kò si ọjọ́ ti ilú yà sọ́tọ̀ fún Ìdúpẹ́, ṣùgbọ́n lati idilé si idilé, ọjọ́ ọpẹ́ pọ Ki kómọ jade, iṣile, di dé lati àjò láyọ̀, ikórè ni Ìjọ Onigbàgbọ́, ọdún ibilẹ̀ bi Ìjẹṣu àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, mú ọpẹ́ àti ọ̀pọ̀ oúnjẹ dáni Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé Ai jẹun Ológbò kọ́ ni kò jẹ́ kó tó Ajá, bẹni ki ṣe ai jẹun ajá ni kò jẹ́ kó tó Erin Fihàn pé, ki ṣe bi a ti jẹun tó, ni a ṣe nga tó, nítorí kò si bi Ológbò ti le jẹun tó, kó tó Ajá, tàbi ki Ajá jẹun titi kó tó Erin Oúnjẹ púpọ̀ kò mú ara líle wá, nítorí ọ̀pọ̀ àfoògùn-gbin oúnjẹ ayé òde òni lè fa àìsàn A ki àwọn ti ó nṣe Ìdúpẹ́ pé wọn kú ọdún o A gbà wọn ni iyànjú ki wọn jẹun niwọn nítorí ọ̀pọ̀ ló wà ni àgbáyé ti kò ri oúnjẹ lati jẹ Ní ayé àtijọ, Yáníbo ìyàwó Ìjàpá gbìyànjú títí ṣùgbọ́n kò rí ọmọ bí Ní ayé àtijọ, Yáníbo ìyàwó Àjàpá gbìyànjú títí ṣùgbọ́n kò rí ọmọ bí Ọmọ bíbí ṣe pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá, nítorí èyí ìrònú ma mba obìnrin tí kò bá ri ọmọ bi tàbí tí ó yà àgàn Babaláwo se àsèjẹ fún Yáníbo, ó rán Ìjàpá láti lọ gba àsàjẹ yi lọ́wọ́ Babaláwo Ó dé́lé ó gbé irọ́ kalẹ̀ fún ìyàwó, ṣùgbọ́n láìpẹ́ ikùn Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí wú Yorùbá ni ohun ti a ni ki Baba mágbọ, Baba ni yio parí rẹ Bi ikùn ti nwu si bẹni ara bẹ̀rẹ̀ si ni Ìjàpá, ó ba rọ́jú dìde, ó ti orin bẹnu bi o ti nsáré tọ Babaláwo lọ Nígbátí ó dé ilé́ Babaláwo, Babaláwo ni ko si ẹ̀rọ̀ Ikùn Ìjàpá wú títí o fi bẹ, tí ó sì kú Ìtàn yí kọ wa pe èrè ojúkòkòrò, àìgbọ́ràn, irọ́ pípa àti ìwà burúkú míràn ma nfa ìpalára tàbí ikú Ìtàn náà bá gbogbo aláìgbọràn àti onírọ́ wí Òwe yi wúlò lati gba àwọn ènìà tí o gbójúlé ẹbí níyànjú Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rò wípé ẹ̀tọ́ ni ki ẹni tí ó bá lówó nínú ẹbí tàbí tí ó ngbe ni Òkè-Òkun bá wọn gbé ẹrù lai ro wípé ẹbí tí o lówó tàbí gbé l'Ókè-Òkun ní ẹrù tiwọn lati gbé Iṣẹ́ lẹ́ni tí ó wa l'Ókè-Òkun nṣe nínú òtútù Fún àpẹrẹ níbití olówó tàbí àwọn tí ó ngbe Òkè-òkun tí nṣe àwọn nkan níwọnba bí – ọmọ bíbí, aṣo rírà, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbójúlẹ́bí á bímọ rẹpẹtẹ, kó owó lé aṣọ, bèrè ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ olówó nla tí ẹni tí ó wà l'Ókè-Òkun ó lè kó owó lé lórí àti gbogbo àṣejù míràn Ẹbí olówó tàbí tí ó ngbe Òkè-òkun kò lè dípò Ìjọba Ọ̀dọ̀ Ìjọba tí ó ngba owó orí lóyẹ kí á ti bèrè ẹ̀tọ́, ki ṣe lọ́wọ́ ẹbí Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni Bi ọmọdé bá tó ni ọkọ́, à fún lọ́kọ́ Ọkọ́ jẹ irinṣẹ́ pàtàkì fún Àgbẹ̀ Iṣẹ́-àgbẹ̀ ni ó wọ́pọ̀ ni ayé àtijọ́ Nítorí eyi, bi bàbá ti nkọ́ ọmọ rẹ ọkùnrin ni iṣẹ-àgbẹ̀, ni ìyá nkọ́ ọmọ obinrin rẹ ni ìtọ́jú-ile lati kọ fún ilé-ọkọ Iṣẹ́ la fi nmọ ọmọ ọkùnrin, nítorí eyi, bi ọkùnrin bá dàgbà, bàbá rẹ á fun ni ọkọ́ nítorí ki ó lè dá dúró lati lè ṣe iṣẹ́ ti yio fi bọ́ ẹbi rẹ ni ọjọ́ iwájú Bi ọkùnrin bá ni iṣẹ́, ó ku kó gbéyàwó ti yio jẹ Olorì ni ilé rẹ Ìyàwó fi fẹ́ bu iyì kún ọkùnrin, nítorí, ó fi hàn pé ó ni igbẹ́kẹ̀lé Àṣà Yorùbá gbà fún ọkùnrin lati fẹ́ iye ìyàwó ti agbára rẹ bá gbé lati tọ́jú Nítorí eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọba, Baálẹ̀, Ìjòyè àti àwọn enia pàtàkì láwùjọ ma nfẹ ìyàwó púpọ̀ Ìṣòro ni ki wọn fi ọkùnrin ti kò ni ìyàwó jẹ Ọba Kò wọ́pọ̀ ki Ọba ni ìyàwó kan ṣoṣo Ìwúyè Ọba Àkúrẹ́, Olóògbé Ọba Adebiyì Adeṣida Ohun ti a ṣe akiyesi ni ayé òde òni, ni Ọba ti ó fẹ ìyàwó kan ṣoṣo nítorí ẹ̀sìn, pàtàkì ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n ti ó ni àlè rẹpẹtẹ Ọba ayé òde òni ndá nikan lọ si òde lai mú Olorì dáni Gẹgẹbi ọ̀rọ̀ Yorùbá, Àpọ́nlé kò si fún Ọba ti kò ni Olorì, nítorí eyi, kò bu iyì kún Ọba, ki ó lọ àwùjó tàbi rin irin àjò pàtàkì lai mú Olorì dáni Ohun ti ó yẹ Ọba ni ki a ri Ọba àti Olorì rẹ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ Ìtàn ti ó wọ́pọ̀ ni, bi iyá-ọkọ ti burú lai ri ìtàn iyá-ọkọ ti ó dára sọ Eyi dákún àṣà burúkú ti ó gbòde láyé òde òni, nípa àwọn ọmọge ti ó ti tó wọ ilé-ọkọ tàbi obinrin àfẹ́sọ́n�� ma a sọ pé àwọn ò fẹ́ ri iyá-ọkọ tàbi ki iyá-ọkọ ti kú ki àwọn tó délé Ni ayé àtijọ́, agbègbè kan na a ni ẹbi má ngbé – bàbá-àgbà, iyá-àgbà, bàbá, iyá, ẹ̀gbọ́n, àbúrò, ìyàwó àgbà, ìyàwó kékeré, ìyàwó-ọmọ, àwọn ọmọ àti ọmọ-mọ Ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ọ̀pọ̀ kò fẹ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ mọ, ẹbi ti fúnká si ilú nlá àti òkè-òkun nítorí iṣẹ́ ajé àti iṣẹ́-ijọba Ni ọ̀pọ̀ ọdún sẹhin, iyá kan wà ti a o pe orúkọ rẹ ni Tanimọ̀la ninú ìtàn yi Ó bi ọmọ ọkùnrin meje lai bi obinrin Kékeré ni àwọn ọmọ rẹ wà nígbàtí ọkọ rẹ kú Tanimọ̀la fi ìṣẹ́ àti ìyà tọ́ àwọn ọmọ rẹ, gbogbo àwọn ọkùnrin na a si yàn wọn yanjú Nígbàtí wọn bẹ̀rẹ̀ si fẹ́ ìyàwó, inú rẹ dùn púpọ̀ pé Ọlọrun ti bẹ̀rẹ̀ si dá obinrin ti ohun kò bi padà fún ohun Ó fẹ́ràn àwọn ìyàwó ọmọ rẹ gidigidi ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọmọ rẹ kó lọ si ilú miran pẹ̀lú ìyàwó wọn nítorí iṣẹ́ Àbi-gbẹhin rẹ nikan ni kò kúrò ni ilé nítorí ohun ló bójú tó oko àti ilé ti bàbá wọn fi silẹ Nígbàtí ó fẹ ìyàwó wálé, inú iyá dùn pé ohun yio ri ẹni bá gbé Ìyàwó yi lẹ́wà, o si ni ọ̀yàyà, eyi tún jẹ́ ki iyá-ọkọ rẹ fẹ́ràn si gidigidi Yorùbá ni Ẹni a fẹ́ la mọ̀, a ò mọ ẹni tó fẹni Tanimọ̀la kò mọ̀ pé àjẹ́ ni ìyàwó-ọmọ ti ohun fẹ́ràn, ti wọn jọ ngbé yi Bi Tanimọ̀la bá se oúnjẹ, ohun pẹ̀lú ọmọ àti ìyàwó-ọmọ rẹ ni wọn jọ njẹ ẹ Bi ìyàwó bá se oúnjẹ, á bu ti iyá-ọkọ rẹ Kò si ìjá tàbi asọ̀ laarin wọn ti ó lè jẹ ki iyá funra Yorùbá gbà pé ohun burúkú ni ki enia jẹun lójú orun Ni ọjọ́ kan, iyá ké lati ojú orun ni bi agogo mẹrin ìdájí òwúrọ̀, pe ìyàwó-ọmọ ohun ti fún ohun ni oúnjẹ jẹ ni ojú orun Ìyàwó-ọmọ rẹ kò sẹ́, bẹni kò sọ nkan kan Ọkọ rẹ kò gba iyá rẹ gbọ Lati igbà ti iyá ti ké pé ohun jẹ àsáró-iṣu ti ìyàwó-ọmọ ohun gbé fún òhun jẹ lójú orun ni inú rirun ti bẹ̀rẹ̀ fún iyá Inú rirun yi pọ̀ tó bẹ gẹ ẹ ti wọn fi gbé Tanimọ̀la kúrò ni ilé fún ìtọ́jú Wọn gbiyànjú titi, kò rọrùn, nítorí eyi, Tanimọ̀la ni ki wọn gbé ohun padà lọ si ilé ki ohun lọ kú Ki Tanimọ̀la tó kú, ó pe gbogbo ilé lati ge ẹgun fún ìyàwó-ọmọ rẹ pé Òhun jẹ ìyá lóri ọmọ, nígbàtí àsikò àti jẹun ọmọ tó, ìyàwó-ọmọ ṣe ikú pa ohun Nítorí eyi, ìyàwó-ọmọ yi ko ni jèrè ọmọ rẹ, ẹlòmiràn ni yio wo ọmọ rẹ dàgbà Ó ni à fi ti ó bá jẹ ẹ̀ṣẹ̀ ni lati ni ifẹ́ ìyàwó-ọmọ Bi ó ti ge ẹ̀gún tán ni o mi imi ikẹhin ti ó si kú Yorùbá ni Ọlọrun àtijọ́, ló npẹ́ dájọ́, oṣù meje lẹhin ikú Tanimọ̀la, ìyàwó bẹ̀rẹ̀ si rù nítorí kò lè jẹun, kò pẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ àìsàn Ó ni ohun kò lè sùn bẹni ohun kò lè jẹun nítorí iyá-ọkọ kò jẹ́ ki ohun gbádùn Lóri àìsàn ni ó ti bẹ̀rẹ̀ si jẹ́wọ́ pé tòótọ́ ni ohun gbé oúnjẹ ti ohun gbà ninú ẹgbẹ́ àjẹ́ fún iyá-ọkọ ohun Ó pariwo titi ó fi kú Ìtàn yi fihàn pé ẹ̀san mbọ̀ fún oniṣẹ́ ibi Ẹ̀kọ́ ni fún àwon ọmọge òde òni pé, ki ṣe gbogbo iyá-ọkọ ló burú, bó pẹ́ bóyá, ẹ̀san mbọ̀ fún ìyàwó ti ó ni ohun kò fẹ́ ri iya-oko, tàbi ki iyá-ọkọ kú ki ohun tó délé Kò si ibi ti ẹ̀tàn tàbi ká dani kò ti lè wá Ẹni ti ó bá ni iwà burúkú bi ojúkòkòrò, ìlara àti ìmọ-tara-ẹni nikan, lè dani tàbi tan-nijẹ Ọmọ lè tan bàbá tàbi ìyá, ìyá tàbi bàbá lè tan ọmọ, ọkọ lè da aya, ọmọ-ìyá tàbi ẹbi ẹni lè tan ni jẹ, tàbi dani, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìgbà, èniyàn ki reti irú iwà yi lati ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ Nítorí ifi ọkàn tàn si ọ̀rẹ́, ìbànújẹ́ tàbi ẹ̀dùn ọkàn gidi ni fún èniyàn ti ọ̀rẹ́ bá da tàbi tàn jẹ Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ pé, Ọ̀rẹ́ dani kò tó pọ́n, abínibí a má dani Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ pé, Ọ̀rẹ́ dani kò tó pọ́n, ẹbi a má dani Òwe yi fihàn pé kò si ẹni ti kò lè dani tàbi tan ni jẹ, nítorí Àgbẹ́kẹ̀lé enia, asán ló jẹ́ A lè fi òwe yi ṣe ìtùnú fún ẹni ti irònú bá nítorí ọ̀rẹ́ da a, tàbi ti ó sọ ohun ribiribi nù nítorí ẹ̀tàn ọ̀rẹ́ Oriṣiriṣi ènìyàn miran tiki sọmọ Yorùbá pọ ni ìlú nla bi ti Èkó tàbí àwọn olú ìlù nla miran ni agbègbè ilẹ Yorùbá fun àpẹrẹ Abéòkúta, Adó-Èkìtì, Akurẹ, Ìbàdàn, Oṣogbo, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Gẹ́gẹ́bí Wikipedia ti kọ, ni orílẹ̀ èdè Nàíjírià, èdè oriṣiriṣi lé ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lélógún, méjì ninu èdè wọ̀nyí ko si ẹni to nsọ wọn mọ, mẹsan ti parẹ́ pátápáta Eleyi yẹ ko kọwa lọgbọn lati dura ki èdè Yorùbá maṣe parẹ Ilé-ìwé alakọbẹrẹ ti àwọn ènìà nda silẹ A ṣe àkíyèsí wipé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé alakọbẹrẹ ti àwọn ènìà nda silẹ ti ki ṣe ti Ìjọba, kò gba àwọn ọmọ láyè lati kọ tàbi sọ èdè Yorùbá ni ilé ìwè Eleyi lo jẹ ikan ninu ìdí pípa èdè Yorùbá tàbi èdè abínibí yoku rẹ Bí àwọn ọmọ ba délé lati ilé ìwè, èdè gẹẹsi ni wọn mba òbí sọ nítorí ìbẹrù Olùkọ wọn to ni ki wọn ma sọ èdè abínibí Bi òbí ba mba wọn sọ èdè Yorùbá àwọn ọmọ yio ma dahun lédè gẹẹsi Kíkọ, kíkà èdè Yorùbá ko di ọmọ lọ́wọ́ lati ka ìwé dé ipò gíga Ọmọdé lo ma tètè gbọ èdè ti wọn si le yara kọ òbí Ìjọ̀gbọ̀n ni èdè aiyede ma nda silẹ nítorí náà ẹ majẹ ki a di àwọn ọmọ lọ́wọ́ ṣùgbọ́n, ka ran wọn lọ́wọ́ fún ìlọsíwájú èdè Yorùbá Ó sàn ki gbogbo ọmọ tó parí ìwé mẹfa le kọ, ki wọn le kà Yorùbá tàbi èdè abínibí ju pé ki wọn ma le kọ, ki wọn ma lèkà rárá Bi ọ̀pọ̀lọpọ̀ oníṣé ọwọ́, oníṣòwò àti àgbẹ̀ bá lè kọ́ lati kọ àti lati ka èdè Yorùbá ni ilé-ìwé ẹ̀kọ́ àgbà tàbi lẹ́hìn ìwé-mẹ́fà, á wúlò fún ìlú Fún àpẹrẹ, wọn a le kọ orúkọ ní Ilé Ìfowópamọ́, kọ ọjọ́ ìbí ọmọ wọn sílẹ̀, kọ nípa iṣẹ́ wọn sí ìwé àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ìwà alajẹtan ti bori iránti ohun ti Kérésìmesì wà fún Ọ̀pọ̀ kò ti ẹ̀ ránti pé iránti ọjọ́ ibi Jésù ni Ìjọba ṣe fún ará ilú ni ọjọ́ ìsimi ni ọjọ́ karun-din-lọgbọn oṣù kejila ni ọdọ-ọdún Ọ̀pọ̀ ọmọdé ni Òkè-Òkun ti ẹ rò pé Bàbá-Kérésì dára ju Jésù nítorí Bàbá-Kérésì fún àwọn ni ẹ̀bùn ṣùgbọ́n ó kù si ọwọ́ òbi àti àwọn Onigbàgbọ́ lati tẹra mọ́ àlàyé ohun ti ọdún Kérésìmesì wà fún Kò yẹ ki Kérésìmesì sún èniyàn si igbèsè tàbi fa irònú Àwọn ti ó wà ni Òkè-Òkun, ìwà-alẹjẹtan ti sún ọ̀pọ̀ si igbèsè, tàbi irònú nítorí wọn kò ni owó lati ra ẹ̀bùn àti ohun tuntun ti wọn polówó tantan lóri ẹrọ-isọ̀rọ̀ igbàlódé bi ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán, ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsi àti ori ayélujára Òwe Yorùbá ni Ohun ti ó ntán lọdún eégún, eyi túmọ̀ si pé, Ohun ti ó ni ibẹ̀rẹ̀, ni òpin Kérésìmesì ọdún yi ti wá, ó ti lọ, fún àwọn ti ó jẹ igbèsè nítorí ọdún, ó ku igbèsè lati san wọ ọdún tuntun Ni àsikò ìpalẹ̀mọ́ ọdún tuntun yi, ó yẹ ki èniyàn ṣe ipinu lati ṣe bi o ti mọ Ọdún tuntun á bá wa láyọ̀ o Yorùbá ni Ibi ti ẹlẹ́kún ti nsun ẹkún ni aláyọ̀ gbe ńyọ́ Òwe yi fihan ohun tó nṣẹlẹ̀ ni àgbáyé Bi ọ̀pọ̀ àwọn ti ó wà ni Òkè-òkun ti nra ẹ̀bùn àti ọ̀pọ̀ oúnjẹ ni oriṣiriṣi fún ọdún, bẹni àwọn ti kò ni owó lati ra oúnjẹ pọ ni àgbáyé Eyi ti ó burú jù ni àwọn ti ó wà ninú ibẹ̀rù pàtàkì àwọn Onígbàgbọ́ ti kò lè lọ si ile-ijọsin lati yọ ayọ̀ ọdún iranti ọjọ́ ibi Jésù nítorí ibẹ̀rù àwọn oniṣẹ ibi Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni Ori bí bẹ́, kọ́ ni oògùn ori-fí fọ́ Bawo ni pi pa èniyàn nítorí kò gba ẹ̀sìn ṣe lè mú ki èrò pọ̀ si ni irú ẹ̀sìn bẹ́ ẹ̀ Òkè-Ọya ni Àriwá Nàíjírià, Boko Haram npa èniyàn pẹ̀lú ibọn àti ohun ijà ti àwọn ti ó ka iwé ṣe, bẹni wọn korira, obinrin, iwé kikà, ẹlẹ́sìn- ìgbàgbọ́ ni Òkè-Ọya àti ẹni ti ó bá takò wọn pé ohun ti wọn nṣe kò dára Pi pa èniyàn kọ ni yio mu ki àwọn ará ilú gba ẹ̀sìn A ki àwọn iyá àti bàbá àwọn ọmọ obirin ilú Chibok ti wọn ji kó lọ́ ni ilé-iwé, àwọn ẹbi ti ó pàdánù ọmọ, ìyàwó, ọkọ, ẹbi, ará àti ọ̀rẹ́ lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ibi – Boko Haram, pé ki Ọlọrun ki ó tù wọn ninú A fi àsikò ọdún Keresimesi mú òbi àwọn ọmọbinrin ilé-iwé Chibok ti won ji ko, lọ́kàn le, pé ki wọn ma ṣe sọ ìrètí nù, nítorí bi ẹ̀mi bá wà ìrètí nbẹ A lè lo òwe yi lati ṣe ikilọ̀ fún ẹni tó fẹ́ lọ si Òkè-òkun lọ́nà kọ́nà lai ni àṣẹ tàbi iwé ìrìnà Bi ẹbi, ọ̀rẹ́ tàbi ojúlùmọ̀ tó mọ ewu tó wà ninú igbésẹ̀ bẹ ẹ bá ngba irú ẹni bẹ niyànjú, a ma binú pé wọn kò fẹ́ ki ohun ṣoriire Bi oúnjẹ ti pọ̀ tó ni ààtàn fún òròmọ adìẹ bẹni ewu pọ̀ tó, nítorí ààtàn ni Àṣá ti ó fẹ́ gbé adìẹ pọ si Bi ọ̀nà àti ṣoriire ti pọ̀ tó ni Òkè-òkun bẹni ewu àti ìbànújẹ́ pọ̀ tó fún ẹni ti kò ni àṣẹ ìrìnà Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkú sọ́nà, ọ̀pọ̀ ndé ọhun lai ri iṣẹ́, lai ri ibi gbé tàbi lai ribi pamọ́ si fún Òfin nítorí eyi, ọ̀pọ̀ wa ni ẹwọn Lati padà si ilé á di ìṣòro, iwájú kò ni ṣe é lọ, ẹhin kò ni ṣe padà si, nítorí ọ̀pọ̀ ninú wọn ti ju iṣẹ́ gidi silẹ̀, òmiràn ti ta ilé àti gbogbo ohun ìní lati lọ Òkè-òkun Bi irú ẹni bẹ́ ẹ̀ ṣe npẹ si ni Òkè-òkun bẹni ìtìjú àti padà sílé ṣe npọ̀ si Òwe Yorùbá ti ó sọ pé A ngba òròmọ adìẹ lọ́wọ́ ikú, ó ni wọn ò jẹ́ ki ohun lọ ààtàn lọ jẹ̀ yi kọ́wa pé ká má kọ etí ikún si ikilọ̀, ká gbé ọ̀rọ̀ iyànjú yẹ̀wò, ki á bà le ṣe nkan lọ́nà tótọ́ Orin yi fi bi Yorùbá ti ka iṣẹ abínibí àkọ́kọ́ si hàn Olùkọ́, a má kọ àwọn ọmọ ilé-iwé alakọbẹrẹ ni orin yi lati kọ wọn bi iṣẹ́-àgbẹ̀ ti ṣe kókó tó, nítorí eyi, bi wọn ti nkọ́ iwé, ki wọn kọ́ iṣẹ́-àgbẹ̀ pẹ̀lú Olùpàṣẹ, ọ̀gá ninú Olórin Olóyè Ebenezer Obey fi òwe Yorùbá ti ó sọ pé Bi ebi bá kúrò ninú ìṣẹ́, ìṣẹ́ bùṣe kọrin Àgbẹ̀ ni ó npèsè oúnjẹ ti ará ilú njẹ àti ohun ọ̀gbin fún tità ni ilé àti si Òkè-òkun Owó Àgbẹ ni Nàíjíríà fi ja ogun-abẹ́lé fún ọdún mẹta lai yá owó ni bi ọdún mẹtadinlaadọta titi di ọdún mẹrin-le-logoji sẹhin Lẹhin ogun-abẹ́le yi, Naijiria ri epo-rọ̀bì ni rẹpẹtẹ fún tita si Òkè-òkun Dipò ki wọn fi owó epo-rọ̀bì yi pèsè ẹ̀rọ oko-igbálódé fún àwọn Àgbẹ̀ lati rọ́pò ọkọ́ àti àdá, ṣe ni wọn fi owó epo-rọ̀bì ra irà-kurà ẹrù àti oúnjẹ lati Ò̀kè-òkun wọ ilú Eyi ló fa ifẹ́-kufẹ si oúnjẹ àti ohun ti ó bá ti Oke-okun bọ̀ titi di òni Gẹ́gẹ́ bi Ọba-olórin Sunny Ade ti kọ́ lórin pé Kò si Àgbẹ̀ mọ́ lóko, ará oko ti dari wálé Gbogbo ará oko ti kúrò lóko wá si ilú nlá lati ṣe iṣẹ́-oṣù tàbi iṣẹ́-Ìjọba dipò iṣẹ́-àgbẹ̀ Owó iná-kuna yi sọ ọ̀pọ̀ di ọ̀lẹ nítorí ó rọrùn lati ṣe iṣẹ́ oṣù ni ibòji ilé-iṣẹ́, lẹhin iwé-mẹfa tàbi iwé-mẹwa ju ki wọn ṣe iṣẹ́-àgbẹ̀ lọ Òwe Yorùbá ti ó ni Iṣẹ́ loògùn ìṣẹ́ kò bá ohun ti o nṣẹ lẹ̀ ni ayé òde òni lọ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣìṣẹ́-Ijọba tàbi oniṣẹ́-oṣù wà ninú ìṣẹ́, nítorí wọn kò ri owó gbà déédé mọ, bẹni àwọn ti ó fẹhinti lẹ́nu iṣẹ́ kò ri owó-ifẹhinti gbà nítorí Ìjọba Ológun, Òṣèlú àti Ọ̀gá ilé-iṣẹ́ ngba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wọn nja ilé-iṣẹ́ àti ilú ló olè nípa ki kó owó jẹ Oriṣiriṣi iṣẹ́-ọwọ́ àti òwò ló wà yàtọ̀ si iṣẹ́-àgbẹ̀ Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ pé, Ọ̀nà kan kò wọ ọjà, ló mú telọ tó nta ẹ̀kọ Ohun ti oniṣẹ́-oṣù àti òṣiṣẹ́-Ìjọba lè ṣe lati lo iṣẹ́ fún oògùn ìṣẹ́ ni, ki wọn ni oko lẹgbẹ pẹ̀lú iṣẹ́-oṣù tàbi ki wọn kọ́ iṣẹ́-ọwọ́ miran ti wọn lè ṣe lẹhin ifẹhinti Àwọn ọ̀nà oríṣiríṣi ni a le fi gbé àṣà Yorùbá àti lílò iṣẹ́ ọ̀nà ni ilẹ̀ Yorùbá jáde lórí ẹ̀rọ-alántakùn Onírúurú ìṣe ọ̀nà ni a le fi sí ẹ̀rọ-alántakùn bí i sinimá, àwòrán, ọ̀rọ̀ aláìláwòrán, ọrin àti ìtàn ti ayé àtijọ́ A máa fi àṣà Yorùbá hàn sí gbogbo ènìyàn lórí ẹ̀rọ-alántakùn nípa fífi gbogbo ohun tí ó dára gan hàn ni nínú ilẹ̀ Yorùbá àti ilẹ̀ Áfíríkà Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láàyé máa rí ilẹ̀ Áfíríkà bí o ti ṣe rí gan gan Lóde òní á rí ohun gẹ̀ẹ́sì púpọ̀ lórí ẹ̀rọ alántakùn sùgbọ́n à á rí ohun Áfíríkà díẹ̀, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ Áfíríkà tóbi gan an ni Nítorí náà a ní ànfàànì láti gbé ìṣe Yorùbá jáde nípaṣè ẹ̀rọ alántakùn Ó máa gbé àṣà Yorùbá jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára fún gbogbo ènìyàn láti rí gbogbo ohun tí ó dára nípa ilẹ̀ Yorùbá àti ilẹ̀ Áfíríkà A le máa wá lórí Google Search láti rí púpọ̀ nípa àṣà Yorùbá bí i èdè, àwòrán, àpóti-amóhùn-máwòrán, ìròyìn àti ìtàn Yorùbá oríṣiríṣi Ọ̀nà dáradára wọ́nyìí ni láti bá ara ẹni sọ̀rọ̀ nípa ìṣe Yorùbá, a sì fi gbogbo náà hàn sí àwọn láayé Láìpẹ́ ẹ̀rọ ayélujára máa ṣe ju láti yára wá rí ìṣe Áfíríkà fún ilẹ̀ Náíjíríà Ẹ̀kọ́ kíkọ́ ni ó lè fún àgbà ni ọgbọ́n àti òye lati lè sọnú Oriṣiriṣi ọ̀nà ni a lè fi gbà kọ́ ẹ̀kọ́, ṣugbọn ni ayé òde òni, ohun gbogbo ni a lè ri kọ́ ni orí ayélujára Bi ayélujára ti sọ ayé di ẹ̀rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ló tún bayé jẹ́ si Àwọn ọmọ ìgbàlódé mọ èlò ẹ̀rọ ayélujára ju àgbàlagbà lọ Àgbà ti kò bá ni ìfura, ki o si kọ ẹ̀kọ́ lilo ẹ̀rọ ayélujára á sọnù Ki ṣe orí ẹ̀rọ ayélujára nikan ni ó ti yẹ ki àgbà ma fura ki o ma ba sọnù Àgbà ni lati ṣe akiyesi àwọn ohun wọnyi ṣọ́ra fún àwọn Òṣèlú nípa ṣi ṣọ́ ìbò ti a di dáradára, owó ni ilé ifowó-pamọ́, wi wo àyíká fún amin ewu ti o le wa ni àyíká, ṣi ṣọ irú ounjẹ ti o yẹ ki a jẹ, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Iyán ni oúnjẹ gidi fún Ijẹṣa, nítorí wọn ni iṣu ju ọ̀gẹ̀dẹ̀ lọ Òwe àtijọ́ ni pé Kò si ohun a nfi ọ̀gẹ̀dẹ̀ ṣe ni Ijeṣa, ẹiyẹ ló njẹ́ nítorí ọ̀pọ̀ ohun ni a lè fi ọ̀gẹ̀dẹ̀ ṣe, ni ayé òde òni, ṣùgbọ́n olówó ló njẹ́ nítorí ó wọ́n Ọ̀gẹ̀dẹ̀ yára lati sè, fún àpẹrẹ, ká fi ọ̀gẹ̀dẹ̀ din dòdò, ó ṣe dani kan jẹ ni àjẹ yó, tàbi jijẹ pẹ̀lú oúnjẹ miran bi dòdò àti ẹyin, dòdò àti ẹwa, dòdò àti irẹsi-ọlọ́bẹ̀ àsèpọ̀ funfun Lí lo ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú fún àmàlà, sisè jẹ, tàbi sísun dára fún àwọn ti ó ni àrùn-àtọ̀gbẹ Ọmọdé fẹ́ràn dòdò Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú oúnjẹ ti a lè fi iṣu ṣe, ni a lè fi ọ̀gẹ̀dẹ̀ ṣe Fún àpẹrẹ, ẹ ṣe àyẹ̀wò díẹ̀ ninú àwọn oúnjẹ wọnyi Ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ́ èso ti ó wọ́pọ̀ lára àwọn ohun ọgbin ti a lè ri ni ilẹ̀ Yorùbá pàtàkì ni agbègbè Okitipupa ni ìpínlẹ̀ Ondo Ọ̀gẹ̀dẹ̀ pé oriṣiriṣi, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà ni à nsè fun jijẹ, nígbàtí ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ dára fún jijẹ bi èso lai sè Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà tóbi ju ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ lọ Ni ayé àtijọ́, ohun ọgbin ti ó bá pọ̀ ni agbègbè ni èniyàn ma njẹ, nítorí ko si ọkọ̀ tàbi ohun irinna tó yá lati kó irè oko kan lọ si ekeji Eleyi jẹ ki àwọn ti iṣu pọ ni ọ̀dọ̀ wọn lo iṣu lati ṣe oúnjẹ ni oriṣiriṣi ọ̀nà, àwọn ti o ni àgbàdo púpọ nlo fún onírúurú oúnjẹ ti a lè fi àgbàdo ṣe, àwọn ti ó ni ẹ̀gẹ́ ma nlo lati ṣe oriṣiriṣi oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ Ìyàtọ laarin iṣu ati ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni pé, wọn wa iṣu ninú ebè nígbàtí wọn nbẹ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ lóri igi rẹ Kò si ìyàtọ̀ laarin Èlùbọ́ iṣu àti Èlùbọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀, ṣugbọn bi a bá ro fun àmàlà, àmàlà iṣu dúdú díẹ ju èlùbọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ gbigbẹ, àmàlà, ọ̀gẹ̀dẹ̀ tútù kò dúdú ó pọ́n fẹ́rẹ́fẹ́ Iṣu tútù kò ṣe e bùṣán nítorí yio yún èniyàn ni ọ̀fun, nibi ti ó burú dé, bi omi ti wọn fi fọ iṣu bá ta si ni lára, yio fa ara yin yún Gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá ti ó ni Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú kò yá bù ṣán, ọmọ burúkú kò yá lù pa, ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú kò dùn lati jẹ ni tútù, eyi ti ó bá ti kẹ̀ naa kò ṣe é jẹ, ṣùgbọ́n ọ̀gẹ̀dẹ̀ ti ó pọ́n ṣe jẹ ni pi pọ́n lai sè nítorí adùn rẹ Àti ewé àti èso ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni ó wúlò fún jijẹ Bi inú ọpọ ti ndùn, ni inú ẹlòmíràn mbàjẹ́ ni àsikò òjò Yorùbá ni orin fún igbà ti kò ba si òjò, igbà ti òjò bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ si rọ̀, tàbi ti ó bá nrọ̀ lọ́wọ́ àti bi òjò bá pọ̀jù Ẹ gbọ́ àwọn orin wọnyi pàtàkì bi àwọn ọmọ ilé-iwé alakọbẹrẹ ti nkọ orin òjò Ọ̀rọ̀ àgbọ́sọ, pé wọn fẹ́ sún ọjọ́ idibò siwájú lu jade ni kété ti ọjọ́ idibò kù bi ọ̀sẹ̀ mẹta Iroyin yi kọ́kọ́ lu jade lẹ́nu Ọ̀gágun Dasuki, Onimọ̀ràn Aabo fún Olóri-Òṣèlú Nàíjíríà Jonathan Goodluck Ó ni àwọn Ológun fẹ́ fi ọ̀sẹ̀ mẹfa dojú ijà kọ Boko Haram, ẹgbẹ́ burúkú ti ó ti gba àwọn ilú ni Òkè-Ọya, Nàíjíríà lati bi ọdún marun Nítorí eyi, kò lè si àyè fún àwọn Ológun lati sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọpa lati pèsè àbò ni àsikò idibò ti wọn ti fi si oṣù keji ọdún, ọjọ́ kẹrinla Nígbàtí Olóri-Òṣèlú pe ipàdé àwọn àgbàgbà, ọ̀pọ̀ àwọn ará ilú tu jade lati tako si sún ọjọ́ idibò siwájú Ọ̀gá ilé-iṣẹ́ Alabojuto ètò idibò, Ọ̀jọ̀gbọ́n Attahiru Jega, ṣe àlàyé fún àwọn Akọ̀wé-iroyin pé, Ìjọba sọ pé wọn kò lè dá aabo bo àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún ti àwọn yio gbà si iṣẹ́ àti ará ilú ti ó fẹ dibò ni àsikò idibò Ó ni Ìjọba ni àwọn fẹ fi ọ̀sẹ̀ mẹfa fi taratara dojú ijà kọ Boko Haram, nítorí eyi, Ọ̀jọ̀gbọ́n Attahiru Jega, sọ wipé àwọn kò lè fi ẹ̀min àwọn òṣìṣé àti ará ilú wewu, nítorí náà wọn gbà lati sún ọjọ́ idibò siwájú Ọjọ́ idibò tuntun lati yan Olóri-Òṣèlú yio wáyé ni ọjọ́ keji-din-lọgbọn, oṣù kẹta, idibò lati yan Gómìnà yio wáyé ni ọjọ́ kọ-kànlá oṣù kẹrin ọdún Ẹgbàálemẹ́ẹdóg��n Kiló ṣe ti Ìjọba kò fi taratara jà lati da aabo bo ilú lati bi ọdún marun Òwe Yorùbá so wipe Onígbèsè tó dá ogún ọdún, kò mọ̀ pé ogún ọdún nbọ̀ wá ku ọ̀la, nítorí náà, ki àwọn ará ilú fi ọwọ́ wọ́nú, nítorí ọjọ́ tuntun wọnyi súnmọ́ etíle Ìgbà tàbi àsikò méjì ló wà ni ọ̀pọ̀ ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú, ìgbà òjò àti ẹ̀rùn Ni ayé àtijọ́, òjò ni ará ilú gbójúlé lati pọn omi silẹ̀ fún ọ̀gbẹlẹ̀ Àsikò òjò ṣe pàtàkì fún iṣẹ́-àgbẹ̀, omi pi pọn pamọ́ fún li lò, àti fún ìtura lọ́wọ́ ooru Ẹ̀rọ wi wa epo rọ̀bì A lè fi ìgbà òjò wé ìgbà ti orilẹ̀ èdè Nàíjíríà pa owó rẹpẹtẹ lori epo rọ̀bì lai fi owó pamọ́ Lati ìgbà ti epo rọ̀bì ti gbòde, ilú ko kọ ara si iṣẹ́ àgbẹ̀ àti àwọn iṣẹ́ miran ti ó lè pa owó wọlé Àwọn Ìjọba Ológun àti Alágbádá, bẹ̀rẹ̀ si ná owó bi ẹni pé ìgbà ẹ̀rùn kò ni dé Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti ji jà ilú ni olè, kò jẹ ki òjò owó epo rọ̀bì rọ̀ kári Pẹ̀lú gbogbo owó epo rọ̀bì rẹpẹtẹ, iwà ibàjẹ́ pọ̀ si, kò si ọ̀nà ti ó dára, ilé-iwé bàjẹ́ si, ilé-iwòsàn kò ni ẹ̀rọ igbàlódé, ilú wà ni òkùnkùn nítorí dákú-dáji iná-mọ̀nàmọ́ná àti ìnira yoku Òwe Yorùbá sọ wipé Òjò nrọ̀, Orò nké, atọ́kùn àlùgbè ti ò láṣọ méjì a sùn ihòho Ìtumọ̀ òwe yi ni pé Ẹni ti kò bá pọn omi de òùngbẹ nigbà òjò , a jẹ ìyà rẹ ni ìgbà ẹ̀rùn A lè fi òwe yi ṣe ikilọ fún àwọn Òṣèlú Alágbádá ti ó nkéde fún ibò ni lọ́wọ́lọ́wọ́ pé àtúnṣe ṣi wà lati rán aṣọ kọjá méjì fún ará ilú Ni àsikò ẹ̀rùn ti owó epo rọ̀bì fọ́ yi, ó yẹ ki àwọn Òṣèlú lè ronú ohun ti wọn lè ṣe lati yi ìwà padà kúrò ni inákuná àti lati ronú ohun ti wọn lè ṣe lati pa owó wọlé kún owó epo rọ̀bì, ki ilú lè rọgbọ lọ́jọ́ iwájú Ni ayé àtijọ́, òbi si òbi àti ẹbi si ẹbi ló nṣe ètò ìyàwó fi fẹ́ fún ọmọ ọkùnrin ti ó bá ti bàláágà, ti wọn rò pé ó lè tọ́jú ìyàwó Obinrin ki tètè bàláágà, nítorí ki wọn tó bẹ̀rẹ̀ si ṣe nkan oṣù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ obinrin ma ndàgbà tó bi ọdún mẹrindinlógún tàbi jù bẹ́ ẹ̀ lọ Gẹgẹ bi wọn ti ma nsọ ni igbà igbéyàwó ibilẹ òdòdó kán wà lágbàlá ti a fẹ́ já, bi òbi tàbi ẹbi bá ṣe akiyesi ọmọ obinrin ti ó wù wọn lati fẹ́ fún ọmọ ọkùnrin wọn, yálà idilé si idilé tàbi ni agbègbè ni ibi ọdún omidan, wọn yio lọ bá òbi obinrin na a lati bẹ̀rẹ̀ ètò bi wọn yio ti fẹ fún ọmọ wọn Ni ayé igbàlódé, obinrin yára lati bàláágà, nítorí omiran a bẹ̀rẹ̀ nkan oṣú ni bi ọmọ ọdún mọ́kànlá Obinrin ki yára fẹ́ ọkọ mọ nítorí ilé-iwé àti pé ki ṣe òbi àti ẹbi ló nfẹ́ obinrin fún ọmọ ọkùnrin mọ Yorùbá ma nlò ọ̀rọ̀ ti ó sọ pé Ọ̀kan-lé-nigba lọkọ ọmọge, ikan ori rẹ ni ọkọ gidi lati la obinrin lóye pé ki ṣe gbogbo ọkùnrin ti ó bá wá bá obinrin lati sọ̀rọ̀ ifẹ́ ló ṣe tán lati fẹ́ ìyàwó, gbogbo wọn kọ́ si ni ọkọ gidi Kò yẹ ki obinrin kanra tàbi lé ọkùnrin ti ó bá kọ ẹnu ifẹ́ si wọn pẹ̀lú èébú, nítorí Yorùbá sọ wipé, A kì í kí aya-ọba kó di oyún ṣùgbọ́n ki wọn farabalẹ̀ lati mọ irú ẹni ti ọkùnrin na a jẹ Li lé ọkùnrin nígbàtí ọ̀pọ̀ ọkùnrin bá fẹ́ yan obinrin lọrẹ, pàtàkì ni igba ti obinrin bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bàláágà, lè fa ki obinrin ṣe àṣimú ni igba ti wọn bá ṣe tán lati fẹ́ ọkọ, nítorí ó ti lè bọ́ si àsikò ikánjú Ki ṣe obinrin nikan ni ọ̀rọ̀ Yorùbá wọnyi bá wi, ó bá ọkùnrin na a wi Ọkùnrin miran á fi àárọ̀ ṣeré nítorí wọn rò wipé àsikò wà fún wọn, nítorí eyi, wọn á gbé obinrin kan, ju ikan silẹ̀ titi wọn yio fẹ́ obinrin burúkú Eyi ti ó tún wọ́pọ̀ láyé òde oni ni wipé, ọkùnrin miran kò mọ obinrin ti ó ti lọ́kọ yàtọ̀ si ọmọge, nípa ki kọ ẹnu ifẹ́ si gbogbo obinrin, eleyi lè fa àkóbá fún ọkùnrin Eyi ti ó ṣe pàtàkì ni ki ọkùnrin àti obinrin bọ̀wọ̀ fúnra Ibò ni gbogbo orilẹ̀ èdè Nàíjíríà lati yan Olóri Òṣèlú àti Gómìnà fún agbègbè yio wáyé ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrinla, oṣù keji odun Ẹgbàálemẹ́ẹdógún Òwe yi bá ọpọlọpọ Yorùbá tí o nyi orúkọ ìdílé wọn padà nítorí ẹ̀sìn lai yi ìwà padà̀ lati bá orúkọ titun áti ẹ̀sìn mu Yorùbá ni ilé lanwo ki a tó sọmọ lórúkọ nítorí èyí, ọpọlọpọ orúkọ ìdílé ma nbere pẹ̀lú orúkọ òrìṣà ìdílé bi Ògún, Ṣàngó, Ọya, Èṣù, Ọ̀sun, Ifá, Oṣó àti bẹ́ẹ̀b��́ẹ̀ lọ Fún àpẹrẹ Ògúnlànà, Fálànà, Ṣólànà ti yi padà sí Olúlànà Ìgbà míràn ti wọn bá lò lára orúkọ àwọn òrìṣa yi wọn a ṣe àyípadà si, fún àpẹrẹ Eṣubiyì di Èṣúpòfo Esupofo Njẹ Èṣù pòfo bí, nígbàtí ẹni ti o yi orúkọ padà sí Èṣúpòfo njale Njẹ Èṣù pòfo bí, nígbàtí ẹni ti o yi orúkọ padà sí Èṣúpòfo njale, ṣiṣẹ́ gbọ́mọgbọ́mọ, purọ́, kówó ìlú jẹ, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ótì o, Èṣù o pòfo, ìwà lọmọ àlè Ọmọ àlè ti pọ si nítorí ìwà Èṣu ti pọ si ni ilẹ̀ Yorùbá Kò sí nkan tí óburú ninú orúkọ yíyí padà, èyí ti o burú ni kí a yí orúkọ padà lai yi ìwà padà Ẹ fi ìwà rere dípò ìporúkodà Yorùbá ki dá gbé, nítorí eyi, ẹbi àti ará á pa pọ̀ lati sọ ọmọ lórúkọ Ni ọjọ́ ìsọmọ-lórúkọ, ki ṣe iyá àti bàbá ọmọ nikan ni ó nmú orúkọ silẹ̀, iyá àti bàbá àgbà àti ẹ̀gbọ́n naa yi o fún ọmọ tuntun lórúkọ Nítorí eyi ọmọ Yorùbá ki ni orúkọ kan wọn ma nni orúkọ púpọ̀ lori iwé-orúkọ Ni ayé òde oni pàtàkì ni òkè-òkun, ọpọ fẹ́ràn à ti fi orúkọ kúkúrú dipò orúkọ gigun ayé àtijọ́ Nítorí à ti pè ni wẹ́rẹ́, ṣùgbọ́n wọn lè fi orúkọ gigùn si aarin àwọn orúkọ yoku Ẹ ṣe àyẹ̀wò diẹ̀ ninú orúkọ kúkúrú Yorùbá ti ó ṣe fún ọmọ ni ojú iwé yi Ni ayé àtijọ́, ki òbí tó gbà lati fi ọmọ fún ọkọ, wọn yio ṣe iwadi irú iwà àti àìsàn ti ó wọ́pọ̀ ni irú idile bẹ́ ẹ̀ Nítorí eyi, igbéyàwó ibilẹ̀ ayé àtijọ́ ma npẹ́ ju ti ayé òde òni Bi ọmọ obinrin bá nlọ si ilé ọkọ, ikan ninu ẹrù tó ṣe pàtàkì ni ki wọn gbé ẹni fún dáni lati fi han pé kò si àyè fun ni ilé òbi rẹ mọ nítorí ó ti di ara kan pẹ̀lú ẹbi ọkọ rẹ Ni idà keji, obinrin ayé òde òni, kò dúró ki òbí ṣe iwadi rara, pàtàkì bi wọn bá pàdé ni ilú nla ti èrò lati oriṣiriṣi ẹ̀yà pọ̀ si tàbi ni ilé-iwé Ọkùnrin ri obinrin, wọn fi ìfẹ́ han si ara wọn, ó pari, ọ̀pọ̀ ki ṣe iwadi lati wo ohun ti àgbà tàbi òbí nwò ki wọn tó ṣe igbéyàwó Obinrin ti lè lóyún ki òbí tó gbọ́ tàbi ki wọn tó lọ si ilé Ìjọ́sìn lati ṣe ètò igbéyàwó Àwọn miran nkánjú, wọn kò lè dúró gba imọ̀ràn Irú imọ̀ràn wo ni òbí tàbi Alufa fẹ́ fún ọkùnrin àti obinrin bẹ́ ẹ̀ Ki ṣe ìfẹ́ ló fọ́jú, ṣùgbọ́n àwọn ti ó wọnú ìfẹ́ ló fọ́jú nítorí, bi obinrin tàbi ọkùnrin miran bá ti ri owó, ẹwà, ipò agbára, wọn á dijú si àlébù miran ti ó wà lára ẹni ti wọn fẹ́ fẹ́ Igbéyàwó ki ṣe ọjà̀ òkùnkùn, ṣùgbọ́n àwọn ti ó nwọ̀ ọ́ ni ó dijú, nítorí nígbàtí àlébù ti wọn dijú si bá bẹ̀rẹ̀ si jade lẹhin igbéyàwó, igbéyàwó á túká Ki ṣe ìfẹ́ ló fọ́jú, ṣùgbọ́n àwọn ti ó wọnú ìfẹ́ ló fọ́jú nítorí, bi obinrin tàbi ọkùnrin miran bá ti ri owó, ẹwà, ipò agbára, wọn á dijú si àlébù miran ti ó wà lára ẹni ti wọn fẹ́ fẹ́ Igbéyàwó ki ṣe ọjà̀ òkùnkùn, ṣùgbọ́n àwọn ti ó nwọ̀ ọ́ ni ó dijú, nítorí nígbàtí àlébù ti wọn dijú si bá bẹ̀rẹ̀ si jade lẹhin igbéyàwó, igbéyàwó á túká Ìmọ̀ràn fún ọkùnrin àti obinrin ti ó nronú lati ṣe igbéyàwó ni ki wọn lajú, ki wọn si farabalẹ̀ ṣe iwadi irú iwa ti wọn lè gbà lati fi bára gbé lai wo ohun ayé bi ẹwà, owó àti ipò nítorí ìwà ló ṣe kókó jù fún igbéyàwó ti yio di alẹ́ Ni ayé àtijọ́, òbi ni o nfẹ ìyàwó fún ọmọ ọkùnrin wọn Bi òbi bá ri ọmọ obinrin ti o dára ni idile ti o dára, wọn á lọ fi ara hàn lati tọrọ rẹ fún ọmọ wọn ọkùnrin Àṣà yi ti yàtọ̀ ni ayé òde òni, nítorí awọn ọmọ igbàlódé kò wo idile tabi gbà ki òbi fẹ́ ìyàwó tabi ọkọ fún wọn Ọkùnrin àti obinrin ti lè má bára wọn gbé – wọn ti lè bi ọmọ, tabi jẹ ọ̀rẹ́ fún igbà pipẹ́ tabi ki wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé, wọn yio fi tó òbi leti bi wọn bá rò pé awọn ti ṣetán lati ṣe ìgbéyàwó Mọ̀ mí, nmọ̀ ẹ́, jẹ ikan ninu ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ninu ètò ìgbéyàwó ibilẹ̀ Yorùbá ni Ẹni tó lọ si ilé àna, lọ sọ èdè òyìnbó, ni yio túmọ̀ rẹ, nítorí eyi ẹbi ọkọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ìgbéraga ni ilé àna bi ó ti wù ki wọn ni ọlá tó Ẹbi ọkọ yio tọ ẹbi ìyàwó lọ lati fi ara hàn ati lati ṣe àlàyé ohun ti wọn ba wa fún ẹbi obinrin Yorùbá ni A ki lọ si ilé arúgbó ni ọ̀fẹ́, nítorí eyi, ẹbi ọkọ yio gbé ẹ̀bùn lọ fún ẹbi ìyàwó Kò si ináwó rẹpẹtẹ ni ètò mọ̀ mí, nmọ̀ ẹ́, nítorí ohun ti ẹbi ọkọ ba di dani ni ẹbi ìyàwó yio gba, ẹbi ìyàwó na yio ṣe àlejò nípa pi pèsè ounjẹ Mọ̀ mí, nmọ̀ ẹ́, o yẹ ki o fa ariwo, nítorí ki ṣe gbogbo ẹbi lo nlọ fi ara hàn ẹbi àfẹ́-sọ́nà A ṣe akiyesi pé awọn ti ó wá ni ilú nlá tabi awọn ọlọ́rọ̀ ti sọ di nkan nla Èrò ki pọ bi ti ọjọ ìgbéyàwó ibilẹ Ẹ ranti pé ki ṣe bi ẹbi bá ti náwó tó ni ó lè mú ìgbéyàwó yọri Ẹ jẹ ki a gbiyànjú lati ṣe ohun gbogbo ni iwọntunwọnsin Eyi ti o ṣe pàtàkì jù ni lati gba ọkọ àti ìyàwó ni ìmọ̀ràn bi wọn ti lè gbé ìgbésí ayé rere Ẹ fọ ẹja, edé àti irú, ẹ dàápọ̀ pẹ̀lú ẹran bibọ, ẹja gbígbẹ, iyọ̀, irú, iyọ̀ igbàlódé àti omi sinú ikòkò kan Ẹ gbe ka iná fún sisè Bi ẹ ti nse lọ, ẹ da epo-pupa sinú ikòkò keji Ẹ yọ epo díẹ̀, ki ẹ da àpọ̀n si lati yọ àpnọ̀ yi, bi ó ba ti gbónọ́ díẹ̀, ẹ da gbogbo èlò ọbẹ̀ inú ikòkò kini ni gbí-gbónọ́ sinú ikòkò keji ti epo àti àpọ̀n wa Ẹ ro pọ, ẹ yi iná rẹ silẹ̀ díẹ, ki ẹ ro titi yio fi jiná Ti ọbẹ̀ na bá ki jù, ẹ bu omi gbi-gbónọ́ díẹ si titi yio ri bi ẹ ṣe fẹ́ Gẹ́gẹ́bí Ọba nínú Olórin ti ógbé àṣà àti orin Yorùbá lárugẹ lagbaaye Ọba orin Sunny Ade ti kọ wípé Kí iṣu tó di iyán a gún iṣu lódó, òdodo ọ̀rọ̀ ni wípé a ni lati gún iṣu lódó kí ó tó di Iyán, ṣùgbọ́n fún ìrọ̀rùn àwọn tí ó ní ìfẹ́ oúnje abínibí tí ó wà ni Ìlúọba, a ò gún iṣu lódó mọ, a ro lórí iná bí ìgbà ti a ro Èlùbọ́ to di Àmàlà ni Ìyàtọ̀ tó wà laarin Èlùbọ́ tó di Àmàlà àti iṣu tó di Iyán tí a rò nínú ìkòkò ni wípé, Àmàlà dúdú, Iyán funfun, ṣùgbọ́n Àmàlà fẹ́lẹ́ ju Iyán lọ A ní lati ṣe àlàyé fún àjòjì wípeí ara iṣu ni Èlùbọ́ tó di Àmàlà ti jáde gẹ́gẹ́bi Iyán ti jáde lára Iṣu Ọbẹ̀ oriṣiriṣi bi ẹ̀fọ́ ẹ̀lẹ̀gúsí, ilá àsèpọ, àpọ̀n, ewédú àti gbẹ̀gìrì, ẹ̀gúsí funfun àti bẹbẹ lọ la lè fi jẹ Iyán àti Àmàlà Bi ẹ̀fọ́ ẹlẹgusi ti jẹ ọ̀rẹ́ gidi fún Iyán laarin gbogbo ọbẹ̀, bẹni gbẹgìrì pẹ̀lú Ewédú jẹ ọ̀rẹ́ gidi fún Àmàlà A ṣe àkíyèsí wípé àwọn Yorùbá ní ilé fẹ́ràn oúnje òkèrè ju oúnje ilẹ̀ wa lọ ju àwọn tí ó wà ni Òkè-òkun Ẹ gbe oúnjẹ Yorùbá lárugẹ, Iyán àti ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ ẹlẹgusi àti Àmàlà pẹ̀lú gbẹ̀gìrì àti Ewédú dún ládùnjù Bi ọkọ ìyàwó bà ti lówó tó ni ó ti lè fi owó si inú àpò ìwé fún owó orí àti àwọn owó ẹbi yókù Ni ayé òde òní, owó fún àpò ìwé méjìlá wọnyi lè bẹ̀rẹ̀ lati Aadọta náírà, ẹbí dẹ̀ lè din àpò ìwé kù lai ṣi àpò ìwé tàbi ka owó inú rẹ̀ Òwe Yorùbá ni Bíbí ire kò ṣe fi owó rà Ìyàwó ìbílẹ̀ ki ṣe iṣẹ́ ọkọ-ìyàwó nikan, bi ẹbí ìyàwó bá wo àwọn ènìà pàtàkì lẹhin ọkọ, inú wọn a dùn ju owó lọ, nítorí wọn a mọ̀ wípé ilé tó dára ni ọmọ wọn nlọ Ọpọlọpọ ẹbí ki gba owó orí mọ, wọn a fún ẹbí ọkọ padà ni àpò ìwé owó orí pẹ̀lú ìkìlọ̀ wípé ọmọ wọn ki ṣe tita, ṣùgbọ́n ki ọkọ àti ẹbi rẹ tọju ọmọ wọn Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun ti àpò ìwé owó wọnyi wà fún ni ojú ìwé yi Ìnáwó nla ni ìgbéyàwó ìbílẹ̀, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá Bi owó ti mọ ni oògùn nmọ, bi agbára ọkọ ìyàwó àti ìdílé bá ti tó ni ìnáwó ti tó Ẹrù ìgbéyàwó ayé òde òní ti yàtọ si ẹru ayé àtijọ́ nítorí àwọn Yorùbá ti o wa ni àjò nibiti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrù yi kò ti wúlò, nítorí èyi ni a ṣe kọ àwọn ẹrù ti a lè fi dipò pàtàkì fún àwọn ti ó wà lájò Ata ṣe pàtàkì ninu àwọn èlò ọbẹ̀ Yorùbá ni Ẹ̀mí ti ò jata, ẹ̀mí yẹpẹrẹ nítorí eyi, lai si ata ninu ọbẹ̀, ọbẹ̀ o pe Ko si ọbẹ̀ Yorùbá ti enia ma jẹ lai ni ata, fún àpẹrẹ wọn ki jẹ ila funfun tàbi Ewédú ti wọn se lai ni ata lai bu ata ọbẹ̀ si Oriṣiriṣi ata Ata-rodo, Ata-ṣọmbọ, Ata-wẹ́wẹ́, Ata-Ijọsin, Tataṣe, Ata gbigbẹ, Ata gígún Àwòrán ata ti ó wá ni ojú ewé yi wọ́pọ̀ ni ọjà Yorùbá Ọbẹ̀ Yorùbá ti wọn fi ata gígún àti èlò ilẹ̀ wa se ki wọn bi ọbẹ̀ ìgbà lódé ti wọn fi èlò okere se Bi nkan ti wọn to ni ilu, a le fi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin náírà se ìkòkò àwọn ọbẹ̀ Yorùbá bi ilá-àsèpọ̀, ẹ̀gúsí funfun, àpọ̀n, àjó àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ fún idile enia mẹfa Ni ìlú Ayégbẹgẹ́, ìyàn mú gidigidi, eleyi mu Ọba ìlú bẹ̀rẹ̀ si sá pamọ́ fún àwọn ará ìlú nítorí kò mọ ohun ti ohun lè ṣe Òjò kò rọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, oorun gbóná janjan, nítorí náà, k�� si ohun ọ̀gbìn ti ó lè hù Ìrònú àti jẹ àti mun bá gbogbo ará ìlú – Ọba, Olóyè, Ọmọdé àti àgbà Yorùbá ni Àgbà kii wà lọ́jà ki orí ọmọ tuntun wọ, nítorí èyí, Ọba sáré pe gbogbo àgbà ìlú àti Àwòrò-Ifá lati ṣe iwadi ohun ti ìlú lè ṣe ki òjò lè rọ̀ Àwòrò-Ifá dá Ifá, ó ṣe àlàyé ẹbọ ti Ifá ni ki ìlú rú Ifá ni ki ìlú mu Erin lati fi rúbọ ni gbàgede ọjà Gẹ́gẹ́bi Ọba-orin Sunny Ade ti kọ́ Ìtàkùn ti ó ni ki erin ma wọ odò, t'ohun t'erin lo nlọ Ọba paṣẹ fún Akéde ki ó polongo fún gbogbo ara ilu pe Ọba yio da ẹnikẹni ti ó bá lè mú Erin wọ ìlú fun ìrúbọ yi lọ́lá Ọ̀pọ̀ gbìyànjú, pàtàkì nítorí ìlérí ti Ọba ṣe fún ẹni ti ó bá lè mu Erin wọ̀lú, wọn sọ ẹmi nu nínú igbó, ọ̀pọ̀ fi ara pa lai ri Erin mú Laipẹ, Ìjàpá lọ bà Ọba àti Olóyè pé ohun yio mú Erin wálé fún ẹbo rírú yi Olú-Ọdẹ rẹrin nígbàtí o ri Ìjàpá, ó wá pa òwe pé À nsọ̀rọ̀ ẹran ti ó ni ìwo, ìgbín yọjú Olú-Ọdẹ fi ojú di Àjàpá, ṣùgbọ́n Ìjàpá kò wo bẹ̀, ó fi ọgbọn ṣe àlàyé fún Ọba Ọbá gbà lati fún Ìjàpá láyè lati gbìyànjú Ìjàpá lọ si inú igbó lati ṣe akiyesi Erin lati mọ ohun ti ó fẹ́ràn ti ohun fi lè mu Ìjàpá ṣe akiyesi pé Erin fẹ́ràn oúnjẹ dídùn àti ẹ̀tàn Nígbàtí Ìjàpá padá, o ṣe Àkàrà-olóyin dání, o ju fún Erin ki ó tó bẹ̀rẹ̀ si sọ ohun ti ó báwá pé àwọn ará ìlú fẹ ki Erin wá jẹ Ọba ìlú wọn nítorí Ọba wọn ti wọ Àjà Àjàpá pọ́n Erin lé, inú ẹ̀ dùn, ohun naa rò wi pé, pẹ̀lú ọ̀la ohun nínú igbó o yẹ ki ohun le jẹ ọba Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọba àti ará ìlú, wọn ṣe gbogbo ohun ti Ìjàpá ni ki wọ́n ṣe Ìjàpá àti ará ìlú mu Erin wọ ìlú pẹ̀lú ọpọlọpọ àkàrà-olóyin, ìlù, ijó àti orin yi Ìyàwó àgbà ni ìdílé ọkọ àti ti ìyàwó ni o ma nṣe aṣájú fún áwọn ìyàwó ilé yoku lati gbé tàbí gba igbá ìyàwó ni ibi ìgbéyàwó ìbílẹ Ni ayé òde oni, a ṣe àkíyèsí wipé, ìdílé ìyàwó àti ọkọ, a san owó rẹpẹtẹ lati gba àwọn ti o yẹ ki a pè ni Adarí Ètò Ijoko fún ẹbi Ìyàwó àti Adarí Ètò Ìdúró fún ẹbi Ọkọ-ìyàwó Lẹhin ti àwọn obìnrin àjòjì yi ti gba owó iṣẹ́, wọn a sọ ara wọn di Ọ̀GÁ, wọn a ma pàṣe, wọn a ma ṣe bí ó ti wù wọn lati tún rí owó gbà lọ́wọ́ àwọn ẹbí mejeeji Nípa ìwà yí, wọn a ma fi àkókò ṣòfò Yorùbá ni Alágbàtà tó nsọ ọjà di ọ̀wọ́n Ko ba àṣà mu lati sọ Aṣojú awọn ìyàwó-Ilé di ALAGA Ipò méjèjì yàtọ sira, ó dẹ yẹ ki o dúró bẹ ẹ nítorí ọ̀gá méjì kò lè gbé inú ọkọ̀ kan Kò si oye ọdún ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú lè lò ni ipò ti wọn lè gbà lẹ́rọ̀ lati kúrò Bi àyè bá gbà wọn, wọn fẹ kú si ori oyè Bi a bá ṣe akiyesi ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú Òkè-Òkun, bi àwọn ará ilú bá ti dibò pé wọn kò fẹ́ wọn nípa yin yan ẹlòmíràn, wọn yio gbà lẹ́rọ̀, lati gbé Ìjọba fún ẹni tuntun ti ará ilú yan, ṣùgbọ́n kò ri bẹ ẹ ni Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú Ohun ti ó jẹ́ ki àwọn Òṣèlú Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú fẹ́ kú si ipò pọ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Olóri Òṣèlú Nàíjíríà, ki ba jẹ ti Ìjọba Ológun tàbi Alágbádá, kò si ẹni tó mọ bàbá wọn ni ilú, ṣùgbọ́n wọn kò kọ́ ọgbọ́n pé ọ̀pọ̀ ọmọ ti wọn mọ bàbá wọn ni àwùjọ kò dé ipó nla ti àwọn dé Ó ṣe é ṣe ki ó jẹ́ wipé ìbẹ̀rù iṣẹ́ ti ó ṣẹ́ wọn ni kékeré ló jẹ́ ki wọn ni ojúkòkòrò lati fi ipò wọn ji owó ilú pamọ́ fún ara wọn, ọmọ àti aya wọn nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ Kò si oye owó ti wọn ji pamọ́ ti ó lè tẹ́ wọn lọ́rùn, eyi ló fa ìbẹ̀rù à ti kúrò ni ipò agbára Ìbẹ̀rù ki ẹni ti ó bá má a gba ipò lọ́wọ́ wọn, ma ṣe ṣe iwadi wọn na a pẹ̀lú, nítorí wọn ò mọ̀ bóyá yio bá wọn ṣe ẹjọ́ lati gba owó ilú ti wọn ji kó padà Kàkà ki ilú gbérí, ṣe ni ọlá ilú nrẹ̀hìn Bi Òsèlú bá ji owó, wọn a ko ọ̀pọ̀ owó bẹ́ ẹ̀ lọ si Òkè-Òkun tàbi ki wọn ri irú owó bẹ́ ẹ̀ mọ́lẹ̀ lóri ki kọ ilé ọ̀kẹ́ aimoye ti ẹni kan kò gbé Ọ̀pọ̀ owó epo-rọ̀bì ló wọlé, ṣùgbọ́n àwọn Òṣèlú àti àwọn olè bi ti wọn njẹ ìgbádùn nígbàtí ará ilú njìyà Lára ìpalára ti ji ja ilú ni olè fa, ni owó Nàíjíríà ti ó di yẹpẹrẹ, àwọn ọdọ kò ri iṣẹ́ ṣe, àwọn ohun amáyé-dẹrùn ti bàjẹ́ tán, oúnjẹ wọn gógó àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ Òwe Yorùbá ti ó ni Ohun gbogbo ki i tó olè fi àlébù ojúkòkòrò, ifẹ́ owó, ��ti à ṣi lò agbára han ni ilú, pàtàkì ni Nàíjíríà Ni ayé igbà kan ri, àwọn ẹranko ni ọjà ti wọn Ni ọjọ́ ọjà, Kìnìún, Ajá, Ìgalà, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, Erin, Ẹkùn, Ìjàpá, Ọ̀kẹ́rẹ́, Eku-Asin, àti àwọn ẹranko yoku gbé irè oko àti ẹrù fún títà wá si ọjà Erin ni Olóri ọjà, Kìnìún ni igbá keji Gbogbo ẹranko mọ àlébù ara wọn Wọn mọ̀ pé Asin fẹ́ràn ijà, bẹni òfófó àti àtojúbọ̀ ni àlébù Ìjàpá Àjàpá, Ọ̀kẹ́rẹ́, Eku-Asin, àti àwọn ẹranko yoku Ni ọjọ́ kan, ijà bẹ́ silẹ̀ laarin Ọ̀kẹ́rẹ́ àti Asin Ki ṣe pé àwọn ẹranko yoku kò lè làjà yi, ṣùgbọ́n wọn rò pé Asin ti tún gbé iṣe rẹ̀ dé nítorí ó fẹ́ràn ijà, nítorí eyi, wọn kò dá si ijà Ìjàpá fi ìsọ̀ rẹ̀ silẹ̀, ó sá lọ wòran ijà Nígbàtí ó dé ibi ijà, ó rò pé Asin lágbára ju Ọ̀kẹ́rẹ́ lọ, ó kó si wọn laarin Eku-Asin kò fẹ́ràn Ìjàpá nítorí ki gbọ tara ẹ, nítorí eyi, inú bi i, ó fi Ọ̀kẹ́rẹ́ silẹ̀, ó kọjú ijà si Ìjàpá Ó fi ibinú gé imú Ìjàpá jẹ Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ si ké igbe pẹ̀lú orin yi nitoÌri ki àwọn ẹranko yoku lè gba ohun lọwọ Asin Òwe yi ṣe é lò lati ṣe àyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ pí pa àjòjì ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú yoku, ti ó bẹ́ sílẹ ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú ni oṣù kẹrin ọdún Ẹgbàálemẹ́ẹdógún Èniyàn dúdú ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú, jẹ ìyà lábẹ́ Ìjọba amúnisìn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún Ìfẹ́ Àlejò ju ara ẹni, jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú jẹ ìyà lábẹ́ Aláwọ̀-funfun lati Òkè-òkun fún ìgbà pi pẹ́ Ojúkòkòrò Aláwọ̀-funfun si ohun ọrọ̀ ti ó wà ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú pọ̀ si, nígbàtí ọkàn wọn balẹ̀ tán, wọn ṣe Ìjọba ti ó mú onílé sìn Ìjọba amúnisìn yi fi ipá gba ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú lati pin fún Aláwọ̀-funfun, wọn ṣe òfin lati ya dúdú sọ́tọ̀, pé dúdú kò lè fẹ́ funfun, wọn bẹ̀rẹ̀ si lo èniyàn dúdú bi ẹrú lóri ilẹ̀ wọn àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ Àwọn èniyàn dúdú kò dákẹ́, wọn jà lati gba ara wọn sílẹ̀ ninú ìyà àti ìṣẹ́ yi, nítorí eyi wọn pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ bẹni wọn gbé àwọn Olóri Aláwọ̀dúdú púpọ̀ si ẹ̀wọ̀n ọdún àimoye Lára wọn ni Nelson Mandela ti ó lo ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni ẹ̀wọ̀n nítorí ijà àti tú àwọn èniyàn rẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ Ìjọba amúnisìn Ki ṣe ẹ̀yà Zulu tàbi ará ilu Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú nikan ló jà lati gba òmìnira lọ́wọ́ Ìjọba Amúnusìn Gbogbo àgbáyé àti ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú yoku dide pọ lati pa ẹnu pọ̀ bá olè wi Ni àsikò ijiyà yi, Ìjọba àti ará ilú Nàíjíríà ná owó àti ara lati ri pé èniyàn dúdú ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú gba òmìnira lóri ilẹ̀ wọn Gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé A kì í fi Oníjà sílẹ̀ ká gbájúmọ́ alápẹpẹ, àwọn ọ̀dọ́ ti ó npa àjòjì lati ilú dúdú yoku fi Ìjọba ti kò ṣe ẹ̀tọ́ sílẹ gbájúmọ́ àjòjì A ri pé lẹhin ti dúdú ti gba Ìjọba lati ọdún mọ́kànlélógún sẹhin, ìṣẹ́ àwọn èniyàn dúdú kò din kù tó, pàtàkì laarin àwọn ọ̀dọ́ Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú kò kọ́ ọgbọ́n ninú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ti àwọn Aláwọ̀-funfun fi mu Aláwọ̀-dúdú sìn Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú n ja ilú lólè, wọn nkó ọrọ̀ ilú lọ si Òkè-òkun, wọn hu iwà ti ó burú bi ti àwọn Amúnisìn si àwọn èniyàn wọn Eleyi ló fa si sá kiri àwọn ọ̀dọ́ lati ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú kan si ekeji tàbi lọ si Òkè-òkun lọ́nà-kọnà A lérò wi pé àwọn àjòjì yio hu iwà ti ó tọ́, ki onilé na a mọ̀ pé Ki á rin ká pọ̀ ló yẹni, pi pa àjòjì kọ ni yio gbà wọn ninú ìṣẹ́ A si tún lérò wi pé Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú yio ni àyipadà ọkàn lati pèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́, pèsè ohun améyédẹrùn igbàlódé àti lati hu iwà rere si ará ilú Ni ọjọ́ kẹrindinlógún, oṣ̀u kẹrin ọdún Ẹgbàálemẹ́ẹdógún, ọwọ́ Ọlọpa Italy tẹ ọkùnrin mẹ́ẹdógún ti ó ju àwọn Ìgbàgbọ́ méjìla si odò nítorí ẹ̀sìn lati inú ọkọ̀ ojú agbami ti o nko Aláwọ̀-dúdú ti ó nsa fún ogun àti iṣẹ lo si Òkè-òkun Ni gbogbo ọ̀nà ni Aláwọ̀-dúdú fi gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn Ọmọ ijọ ti kò le bọ ara rẹ tàbi bọ ọmọ, ti ó nda ida-mẹwa nígbàtí Olóri Ijọ nfi owó yi gun ọkọ̀ òfúrufú fi han pé ọ̀pọ̀ ti gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn Aládurà ti ó nri iran ti kò ri tara rẹ gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn Ẹlẹ́sin Mùsùlùmi ti ó npa ẹlòmíràn ni orúkọ ẹ̀sìn gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn Eyi ti ó ni èèwọ̀ ni iwé kika fún ẹ̀sìn ohun Boko Haram ti wọn fi nba ilé iwé jẹ, ji àwọn obinrin kò kúrò ni ilé iwé, fihàn pé wọn gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn Ọjọ́ kẹrinla oṣù kẹrin ọdún Ẹgbàálemẹ́ẹdógún ló pé ọdún kan ti ẹgbẹ́ burúkú Boko Haram ti ko igba-le-mọkandinlógún obinrin kúrò ni ilé-iwè ni Chibok Lèmọ́mù rán ọmọ tirẹ̀ lọ si ilé-iwé, irú àwọn ọmọ Lèmọ́mù ti ó ka iwé ni ó nṣe Òṣèlú tàbi jẹ ọ̀gá ni iṣẹ́ Ìjọba Kò si Òṣèlú Aláwọ̀-dúdú ti kò sọ pé ohun jẹ Onígbàgbọ́ tàbi Mùsùlùmi ṣùgbọ́n eyi kò ni ki wọn ma ja ilú ni olè Ìfẹ́ agbára ki jẹ ki wọn fẹ gbe ipò silẹ̀ nítorí eyi wọn á fi ẹ̀sìn da ilú rú Eleyi ló fa ogun ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú Kàkà ki Aláwọ̀-dúdú yẹ ara wọn wò, gbogbo ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì fẹ́ kó kúrò ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú lọ si Òkè-òkun Bi gbogbo ará ilú Aláwọ̀-dúdú bá kó lọ si Òkè-òkun pẹ̀lú bi wọn ṣe gba were mo esin, wọn á ba ibẹ̀ jẹ́ Ọjọ́ ti wèrè bá ti mọ̀ pé wèrè ni ohun ni iwòsàn bẹ̀rẹ̀, bi Aláwọ̀-dúdú kò bá mọ̀ pé wọn gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn, kò lè si àtúnṣe ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú Ìkà kò jẹ́ ṣe ọmọ rẹ bẹ́ ẹ̀, ọmọ Olóri Ìjọ, Lèmọ́mù àti àwọn Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú kò si ninú àwọn ti ó nkú si odò nítorí àti lọ si Òkè-òkun ni tipá-tipá Ìwà ikà àti ijà nítorí ẹ̀sìn kò mú ọgbọ́n dáni Ni igbà ipalẹ̀mọ́ idibò, ẹ̀rù ba ará ilú nítorí wọn kò mọ ohun ti ó lè sẹlẹ̀ Àwọn ti ó ndu ipò jade ni rẹpẹtẹ fún ètò-òṣèlú, eyi ti ó fa ki àwọn jàndùkú bẹ̀rẹ̀ ijà ti ó fa sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ pàtàkì ni ilú Èkó, eleyi fa ibẹ̀rù pé ọjọ́ idibò yio burú Ẹgbẹ́ Onigbalẹ Yorùbá ni Ọ̀rọ̀ ki i mi ni ikùn àgbà ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ mi ni ikùn Ọba Èkó, Ọba Rilwanu Akiolu nígbàtí ó ṣe ipàdé pẹ̀lú àwọn àgbà Ìgbò Èkó, pé ti wọn kò bá dibò fún ẹni ti ohun fẹ, wọn yio bá òkun lọ Ọ̀rọ̀ Ọba Rilwanu Akiolu bi ará ilé àti oko ninú Eleyi tún dá kún ibẹ̀rù pé ija yio bẹ́ ni ọjọ́ idibò, nítorí eyi ọpọlọpọ ará ilú ko jade lati dibò Gbogbo àgbáyé ló mọ̀ wi pé àwọn Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú ki i fẹ gbé Ìjọba silẹ Ki ṣe pe wọn ni ifẹ́ ilu,́ bi kò ṣe pé, ó gbà wọn láyè lati lo ipò wọn lati ji owó ilú fún ara àti ẹbi wọn Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá pe Ikú tó fẹ́ pani, bó bá sini ni fìlà, ọpẹ́ ló yẹ ká dá, ikú tó fẹ́ pa ará ilú ti re kọja nítorí ọjọ́ idibò lati yan Gómìnà àti Aṣòfin-ìpínlẹ̀ ti lọ lai mú ogun dáni bi ará ilú ti rò Ẹ ṣe àyẹ̀wò èsi idibò À ṣe kágbá Idibò ni orilẹ̀ èdè Nàíjíríà yio wáyé ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kọkọ̀nlá, oṣù kẹrin ọdún Ẹgbàálemẹ́ẹdógún, lati yan Gómìnà àti àwọn Aṣòfin ìpínlẹ̀ mẹrindinlọ́gbọ̀n A dúpẹ́ pé ilú jade lati dibò yan Olóri Òṣèlú àti àwọn Aṣòfin-àgbà lai mú ijà dáni bi gbogbo ilú ti bẹ̀rù pé yio ri oṣù tó kọjá Yorùbá sọ wi pé Ìbẹ̀rẹ̀ kọ́ ló niṣẹ́ a fi ọ̀rọ̀ yi rọ ará ilú pé ki wọn tu jade lati dibò nítorí Ìjọba àpapọ̀ kò súnmọ́ ará ilú bi ti Gómìnà àti Aṣòfin ìpínlẹ̀ , ki wọn lè jẹ èrè Ìjọba Alágbádá Yorùbá ka ọmọ bibi si ohun pàtàkì fún ìdílé, nítorí èyi, tijó tayọ̀ ni Yorùbá ma fi nki ọmọ titun káàbọ̀ si ayé Gẹ́gẹ́bí Ọ̀gá ninu Olórin ilẹ̀-aláwọ̀ dúdú, Olóyè Ebenezer Obey ti kọ́ Ẹ̀bùn pàtàkì ni ọmọ bibi Ìlú ti igbe ọmọ titun kò bá dún, ìlú naa ́a kan gógó Eleyi lo ṣẹlẹ̀ ni ìlú Olúróhunbí Fún ìgbà pípẹ́, àwọn obinrin ìlú kò ri ọmọ bi, nítorí náà, gbogbo wọn lọ si ọ̀dọ̀ Òrìṣà Ìrókò lati lọ tọrọ ọmọ Oníkálukú wọn jẹjẹ oriṣiriṣi ohun ti wọn ma fún Ìrókò ti wọ́n bá lè ri ọmọ bi Ẹlòmiràn jẹ ẹ̀jẹ́ Ewúrẹ́, òmíràn Àgùntàn tàbi ohun ọ̀gbìn Olúróhunbí ti gbàgbé ẹ̀jẹ́ ti ó jẹ́ Ni ọjọ́ kan, Olúróhunbí dágbére fún ọkọ rẹ̀ pé ohun fẹ́ lọ si oko ẹgàn, ó bá gba abẹ́ igi Ìrókò kọjá Bi ó ti dé abẹ́ igi Ìrókò, Ìrókò gbamú, ó bá sọ di ẹyẹ Ẹyẹ Olúróhunbí bẹ̀rẹ̀ si kọ orin lóri igi Ìrókò bayi Lai pẹ́, àwọn obinrin ìlú bẹ̀rẹ̀ si bimọ Oníkálukú pada si ọ̀dọ̀ Ìrókò lati lọ san ẹ̀jẹ́ wọn, ṣùgbọ́n Olúróhunbí kò jẹ́ mú ọmọ rẹ̀ silẹ lati san ẹ̀jẹ́ ti ó jẹ́ Òwe Yorùbá ni Bi ojú bá sé ojú, ki ohun má yẹ̀ ohun, ṣùgbọ́n Ni igbà kan ri, imú Erin dàbi ti àwọn ẹranko tó kù ni, ṣùgbọ́n Erin fi aigbọ tara ẹni, di o ni imú gigùn Gbogbo nkan tó nlọ ni ayé àwọn ẹranko yoku ni Erin fẹ tọpinpin rẹ Yorùbá ni Ẹni bá wá iwa-kuwa, ojú rẹ á ri irikuri Ni ọjọ́ kan, gẹgẹbi iṣe Erin, ó ri ihò dúdú kan, ó ti imú bọ lati tọpinpin lai mọ pe ibẹ̀ ni Òjòlá fi ṣe ibùgbé Ejò nla ti o ngbe ẹranko tàbi enia mi Bi o ti gbé imú si inú ihò yi ni Òjòlá fa ni imú lati gbe mì Erin pariwo lati tú ara rẹ̀ silẹ̀ ṣùgbọ́n Òjòlá kò tu imú rẹ silẹ̀ Ìyàwó Erin gbọ́ igbe ọkọ rẹ, o fa ni irù lati gbiyànjú ki ó tú ọkọ rẹ silẹ̀ Bi àwọn mejeeji ti ṣe ́gbìyànjú tó, ni imú Erin bẹ̀rẹ̀ si gùn si titi o fi já mọ́ Òjòlá lẹ́nu Imú Erin di gigùn Imú gigùn yi dá itiju fún Erin, ó fi ara pamọ́ titi, ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn ẹranko ti ó kù ri imú rẹ gigun wọn bẹ̀rẹ̀ si ṣe ilara irú imú bẹ Èébú dọlá, ohun itiju di ohun ilara Ọ̀bọ jẹ ẹranko ti ó féràn àti ma ṣe àfarawé gbogbo ẹranko yoku Ni ọjọ́ kan, Ọ̀bọ lọ si ibi ihò dúdú ti Erin lọ lati ṣe ohun ti Erin ṣe Yorùbá ni Ohun ojú wa, lojú nri Bi ó ti gbé imú si inú ihò dúdú yi ni Òjòlá gbe mi, ó si kú Àwọn ẹranko tó kù fi ti Ọ̀bọ kọ́gbọ́n, nítorí eyi ni o fi jẹ imú Erin nikan ló gùn ni gbogbo ẹranko Ẹkọ pàtàkì ninu itàn yi ni pe àfarawé lè fa àkóbá bi ikú òjijì, àdánù owó àti ara, ẹ̀wọ̀n àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Òjò ibùkún lọ́dọ̀ ẹni kan, ni òjò ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ ẹlòmíràn Lai si òjò, ọ̀gbẹlẹ̀ á wà, ọ̀gbẹlẹ̀ pi pẹ́ ló nfa iyàn Inú àgbẹ̀ ma ndun ni àsikò òjò nítorí wọn mọ̀ pé ohun ọgbin wọn yio hù, oúnjẹ àti jẹ, àti tà yio pọ̀ si Ọmọdé àti àgbà ló fẹ́ràn òjò nítorí ó mú ìtura wá, pàtàkì ni igbà ooru Ni idà keji, òjò àrọ̀-irọ̀ dá lè fa ìbànújẹ́ fún àgbẹ̀ àti ará ilú, pàtàkì fún, ẹni ti ilé rẹ njò, ẹni ti ó kọ́lé si ọ̀nà àgbàrá òjò, ó nfá ẹ̀fọn eyi ti ó nfá ibà, àgbàrá lè gbá ohun ọ̀gbìn lọ, agbara lè yalé àti bẹ ́ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ Fún àpẹrẹ, irònú àti ibànújẹ́ ni ìgbà òjò jẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ará ilú Èkó, nítorí ọ̀nà fún àgbàrá kò tó, eyi ma njẹ ki àgbàrá ba ilé àti ọ̀nà jẹ́ Ni Ìbàdàn, irònú na a dé fún àwọn ti ó kọ́lé si ẹ̀gbẹ́ odò Ògùnpa nítorí ìbẹ̀rù omi-yalé Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni Òjò kò bẹni kan ṣọ̀tá, ẹni eji ri leji npa Ọ̀pọ̀lọpọ̀ igbà, òjò kò rọ̀ fún ìbànújẹ́ èniyàn pàtàkì bi èniyàn bá palẹ̀mọ́ fún òjò nípa ti tú àyíká ṣe lai kó pàntí si ọ̀nà àti ojú àgbàrá àti gbi gbẹ́ ọ̀nà fún àgbàrá Òwe Yorùbá sọ wipé Òjò tó rọ̀ ló mú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ wá Pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ dára fún ohun ọ̀gbin bi ìrẹsì àti fún agbo Ẹlẹ́dẹ̀ ṣùgbọ́n kò yẹ ilú Bi Ìjọba bá ṣe ọ̀na fún ọkọ̀ àti ẹlẹ́sẹ̀, pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ á din kù Eyi ti ó ṣe pàtàkì ni ki Ìjọba àti ará ilú sowọ́pọ̀ lati tú agbègbè àti àyíká ṣe lati lè lo òjò fún rere Ilé-ìkàwé gẹ́gẹ́ bi orúkọ yi ti jẹ ni èdè Yorùbá, jẹ ibi ti wọn kó oriṣiriṣi iwé si, fún ọmọ ilé-iwé àti èrò lati wọlé yá iwé fún ki kà Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú ni Ilé-ìkàwé ti bẹ̀rẹ̀ ni Alexandria, Egypt Ni ayé òde òni, ki ṣe iwé nikan ni wọn nkó si Ilé-ìkàwé, wọn a tún pèsè ẹ̀rọ ayélujára fún ẹni ti ó bá fẹ́ ka iwé lóri ayélujára àti lati wá idi ohun ti ó nlọ ni àgbáyé Ilé́-iwé kò pé lai si Ilé-ìkàwé Ki ṣe ilé-iwé nikan ló ni Ilé-ìkàwé, nítorí àdúgbò, agbègbè àti ilú na a ma nni Ilé-ìkàwé fún ọmọ ilé-iwé àti èrò ti ó ni ìfẹ́ lati ni ìmọ̀ Lati igbà ti Ìjọba-àpapọ̀ ti gba gbogbo ilé-iwé lọ́wọ́ àwọn Olùdásílẹ̀, ni ilé-iwé ti bàjẹ́ pàtàkì àwọn ilé-iwé ti Ìjọba gba Yorùbá fẹ́ràn ẹni ti ó bá kàwé, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ìfẹ́ owó àti ìgbádùn ti dipò ìfẹ́ ẹ̀kọ́, nítorí eyi Ilé-àpèjẹ pọ ni ilú ju Ilé-ìkàwé lọ Eyi ti ó burú jù ni pé, kò si Ilé-ìkàwé tuntun, eyi ti ó wà kò ri àtúnṣe Ìròyìn gbe jade pé, Ilé-iṣẹ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ti ṣe tán lati gbé Ilé-ìkàwé ti wọn kọ́ ni ọdún mẹwa sẹhin fún lilò ni ilé-iwé giga ti ó wà ni Àkokà, ilú Èkó, kúrò nítorí wọn ti i pa lati ọdún marun lai lò Eleyi yẹ kó ti ará ilú àti Òṣèlú lójú nítorí, Ilé-ìkàwé ti wọn ti kọ́ ni ọgọrun ọdún sẹhin tàbi jù bẹ ẹ lọ ṣi wà ni Òkè-Òkun Ilú kò lè ni ìlọsíwájú lai si ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ nítorí Ìgbádùn tàbi Eré ṣi ṣe lai ṣi iṣẹ́, ló nfa Ìṣẹ́ Ki i ṣe àkọ́kọ́ ti ọ̀wọ́n epo ọkọ̀ yio wáyé ni Nàíjíríà, ṣùgbọ́n bi ijiyà ti ọ̀wọ́n epo ọkọ̀ kó bá ará ilú bá ti tán, Ìjọba àti ará ilú á gbàgbé ni wéré, wọn ki kọ́ ọgbọ́n lati ronú ohun ti wọn lè ṣe lati jẹ ki irú rẹ ma wáyé mọ Epo ọkọ̀ kò kọ́kọ́ wọ́n nígbàtí Olóri-ogun Abacha gba Ìjọba ni ọdún méjìlélógún sẹhin, ṣùgbọ́n lati bi ogún ọdún, epo ọkọ̀ bẹ̀rẹ̀ si wọn ni ilé-epo nítorí wọn kò tún ilé iṣẹ́ tó nṣe epo ọkọ̀ ṣe, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti iwà ibàjẹ́ pọ̀ fún àwọn ti o nkó epo ọkọ̀ wọlé lati Òkè-òkun àti ilé-epo Ijiyà yi pọ gidigidi, nítorí ọ̀pọ̀ n sun ilé-epo fún ọ̀sẹ̀ kan nítorí àti ri epo ọkọ̀ rà ni oye ti Ìjọba ni ki wọn ta a, ṣùgbọ́n ilé epo gbà lati ta epo fùn alarobọ̀ ju ọlọ́kọ̀ lọ Nígbàtí Olóri-ogun Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ di Olóri-Òṣèlú, ti wọn ri ọ̀rọ̀ ọ̀wọ́n epo ọkọ̀ yanjú, ilú gbàgbé iyà yi Yàtọ̀ si ki àwọn Ọlọ́kọ̀ epo ọkọ̀ da iṣẹ́ silẹ̀, tàbi ki òṣiṣẹ́ ilé-epo rọ̀bì da iṣẹ́ silẹ̀, ọ̀wọ́n epo ti fẹ́ di ìgbàgbé, nítorí irú eleyi ki pẹ́ ju ọjọ́ méjì si mẹta lọ Ẹ ṣe iránti, ni oṣù kini ọdún kẹta sẹhin, nítorí wọn fẹ fi owó kún epo ọkọ̀ lójú ẹ̀rọ, epo ọkọ̀ wọ́n, ṣùgbọ́n bi ilú fẹ́ bi ó kọ̀, Ìjọba Goodluck Ebele Jonathan fi owó kún epo ọkọ̀ lati náírà marunlelọgọta di náírà mẹtadinlọgọrun Ni àsìkò yi, gbogbo èrò bọ́ sita lati sọ tinú wọn pé kò si ohun ti ó yẹ ki wọn gbé epo rọ̀bi lati Nàíjíríà lọ si Òkè-Òkun lati lọ sọ di epo ọkọ̀, ki wọn tún fi owó ko padà silé pẹ̀lú owó iyebiye nígbàtí wọn lè tún ilé-iṣẹ́ to nṣe epo ọkọ̀ ṣe àti lati kọ́ tuntun si Ìjọba ṣe ìlérí fún ará ilú pé àwọn yio lo owó ti wọn bá ri fi tún ohun amáyédẹrùn igbàlódé ṣe, wọn o si kọ àti tún ilé-iṣẹ́ ti o nsọ epo rọ̀bì di epo ọkọ̀ ṣe Ọdún mẹta ti kọjá, Ìjọba kò mú ìlérí yi ṣẹ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti iwà ibàjẹ́ Nàíjíríà wà ni ipò kejila ninú ọrọ̀ ajé epo rọ̀bì ti tà ni àgbáyé Owó epo rọ̀bì mú irọ̀rùn bá ilú nítorí lára owó rẹ ni wọn pin fún Òṣìṣé Ìjọba ni ọdún mọkanlelogoji sẹhin, wọn fi tún ilú ṣe àti pèsè ohun amáyédẹrùn igbàlódé fún ilú eyi ti a mọ̀ si owó Udoji Owó epo rọ̀bì ni orilẹ èdè fi ja ogun abẹ́lé lai jẹ igbèsè, wọn fi kọ́ ile ise ti o nso epo rọ̀bì di epo ọkọ̀ àti epo ìdáná, bẹni wọn pin fún gbogbo ẹ̀yà Nàíjíríà fun ìdàgbàsókè Ìfẹ́ owó lai fẹ́ ṣiṣẹ́ nítorí owó epo rọ̀bì bẹ̀rẹ̀ si ba ilú jẹ́ Gbogbo ará ilú bẹ̀rẹ̀ si gbójúlé owó epo rọ̀bì ju iṣẹ́ àgbẹ̀ tàbi ṣe iṣẹ́ míràn lati kó ọrọ̀ jọ Yorùbá ni Ọ̀mùtín gbàgbé ìṣẹ̀, ará ilú Nàíjíríà ki pẹ́ gbàgbé ìṣẹ́, eyi ló njẹ́ ki Òṣèlú ṣe bi wọn ti fẹ́ Lẹhin ọdún mẹrindinlógún ẹgbẹ́ Alágboòrùn, a lérò wi pé ará ilú yio fún ẹgbẹ́ Onigbalẹ̀ ti ó mbọ̀ ni àyè lati tún ilé-iṣẹ́ ti o nsọ epo rọ̀bì di epo ọkọ̀ ṣe, ki wọn kọ́ tuntun si, din àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti iwà ibàjẹ́ ku Bi kò bá si ìtẹ́lọ́rùn, kò si ohun ti èniyàn ni ti ó tó À i ni ìtẹ́lọ́rùn ló nfa iwà burúkú bi, olè̀ jijà, àgbèrè, ojúkòkòrò, irà-kurà, ijẹ-kújẹ, ìpànìyàn, gbi gbé oògùn olóró àti àwọn àlébù yoku Kò si owó ti ẹni ti kò ni ìtẹ́lọ́rùn lè ni, ki ó tó Yorùbá ni Isà òkú ki i yó, bẹ́ ẹ̀ ló ri fún a lai ni ìtẹ́lọ́rùn, nítorí ojoojúmọ́ ni ohun tuntun njade, pàtàkì ni ayé oriṣiriṣi ẹ̀rọ igbàlódé àti ẹ̀rọ ayélujára yi Fún àpẹrẹ, oriṣiriṣi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ló wà, ti wọn nṣe jade ni ọdọdún, àti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ igbàlódé owó iyebiye Pẹ̀lú ìṣẹ́ ti ó pọ̀ ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú, ọkọ̀ ilẹ́ kò tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú àti Olóri-Ìjọ mọ, ọkọ̀-òfúrufú bi ó ti wọ́n tó, ni wọn nkó jọ Nítorí eyi, kò si owó ti ó lè tó fún ẹni ti ó bá fẹ́ràn ohun ayé Ẹ̀kọ nla ni lati kọ́ ọmọ ni ìtẹ́lọ́rùn lati kékeré Ẹni ti ó bá ni ìtẹ́lọ́rùn, ló ni ohun gbogbo, nítorí ko ni wo aago aláago ṣiṣẹ́, á lè lo ohun ti ó bá ni pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn Pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn, Ohun ti kò tó loni mbọ̀ wá ṣẹ́kù ni ọ̀la bi èniyàn bá lè farabalẹ̀ Ni ayé igbà kan, bi èniyàn bá jẹ́ alágbára, ti ó tẹpá-mọ́ṣẹ́, ti ó si tún ni iwà ọmọlúwàbí, iyì wà fun bi kò ti ẹ ni owó, ju olówó rẹpẹtẹ ti kò si ẹni ti ó mọ idi owó rẹ ni áwùjọ tàbi ti kò hùwà ọmọlúwàbí Ni ayé òde òni, ọ̀wọ̀ wà fún olówó lai mọ idi ọrọ̀, eyi ló njẹ ki irú àwọn bẹ́ ẹ̀ dé ipò Òsèlú, Olóri Ìjọ tàbi gba oyè ti kò tọ́ si wọn Ìbẹ̀rù òṣì lè jẹ́ ki èniyàn tẹpá-mọ́ṣẹ́, bẹ ló tún lè jẹ́ ki ọ̀pọ̀ fi ipá wá owó Ìfẹ́ owó tó gba òde kan láyé òde òni njẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ jalè tàbi wá ipò agbára ti ó lè mú ki wọn ni owó ni ọ̀nà ti kò tọ́ Òṣèlú ki fẹ́ gbé ipò silẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù pé bi agbára bá ti bọ́, ìṣẹ́ dé Àpẹrẹ tani mọ̀ ẹ́ ri pọ̀ lára àwọn Òsèlú ti agbára bọ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọ̀gá Òṣìṣẹ́ Ìjọba ti ipò rẹ bọ́, Olóri Ìjọ ti ó kó ọrọ̀ jọ ni orúkọ Ọlọrun ló nri idá mẹwa gbà ju Olóri Ìjọ ti kò ni owó Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé Òṣì ló njẹ tani mọ̀ ẹ́ ri, owó ló njẹ mo bá ẹ tan fi hàn pé owó dára lati ni, ṣùgbọ́n kò dára lati fi ipá wá ni ọ̀nà ẹ̀bùrú Kò yẹ ki èniyàn fi ojú pa ẹni ti kò ni rẹ́ tàbi sá fún ẹbi ti kò ni, nítorí igbà layé, igb̀a kan nlọ, igbà kan mbọ̀, ẹni ti ó ni owó loni lè di òtòṣì ni ọ̀la, ẹni ti kò ni loni lè ni a ni ṣẹ́ kù bi ó di ọ̀la Nítorí eyi, iwà ló yẹ ká bọ̀wọ̀ fún ki i ṣe owó tàbi ipò Erin jẹ ẹran ti ó tóbi ju gbogbo ẹranko ti a mọ̀ si ẹran inú igbó àti ẹran-àmúsìn, ti a mọ̀ ni ayé òde òni Bi a bá ṣe àyẹ̀wò bi Yorùbá ti ńgé ẹran ọbẹ̀, ó ṣòro lati ro oye ẹran ti enia yio jẹ ki ó tó Erin Bawo ni òwe Yorùbá ti ó ni Bi a bá pẹ́ láyé, a ó jẹ ẹran ti o ́tó Erin ti wúlò fún ẹni ti ki jẹ ẹran ti a mọ̀ si Ajẹ̀fọ́ Àti Ajẹ̀fọ́ àti Ajẹran ni òwe yi ṣe gbà ni iyànjú pé Ohun ti kò tó, ḿbọ̀ wá ṣẹ́ kù Fún àpẹrẹ, bi enia bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nibi kékeré, bi ó bá tẹramọ́, yi o di ọ̀gá, yio si lè ṣe ohun ti ẹgbẹ́ rẹ ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ibi giga ṣe Bi enia bá ni oreọ̀fẹ́ lati pẹ́ láyé, ti ó dúró tàbi ni sùúrù, yio ri pé ohun jẹ ẹran ti ó tó Erin Àgbàdo ni wọn fi nṣe Ògì Ògì ni wọn fi nṣe Ẹ̀kọ́ Ògì ṣí ṣe fẹ ìmọ́ tótó, nítorí eyi, lai si omi, Ògì kò lè ṣe é ṣe Ọkà oriṣiriṣi ló wà ṣùgbọ́n, Ọkà Àgbàdo àti Bàbà ni wọn mọ̀ jù lati fi ṣe Ògì funfun tàbi pupa A lè lọ àgbàdo funfun àti pupa pọ̀, ẹlòmiràn lè lọ ẹ̀wà Sóyà pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bi àpẹrẹ àwòrán ojú iwé yi Ra Àgbàdo lọ́jà Da Àgbàdo rẹ fún ọjọ́ mẹta ninú omi tútù tàbi omi gbi gbóná Ṣọn Àgbàdo kúrò ninú omi lati yọ ẹ̀gbin bi ò̀kúta kúrò Gbe lọ si Ẹ̀rọ fún li lọ̀ tàbi gun pẹ̀lú odó lati lọ ọ Sẹ́ Ògì pẹ̀lú asẹ́ aláṣọ tàbi asẹ́ igbàlódé Bẹ̀rẹ̀ si yọ omi ori Ògì si sẹ bi ó bá ti tòrò Pààrọ̀ omi ori rẹ fún ìtọ́jú rẹ fún ji jẹ tàbi Da Ògì sinú àpò ki ó lè gbẹ fún ìtọ́jú Aṣọ Yorùbá kò pé, lai si Gèlè Bi Yorùbá bá wọ aṣọ ìbílẹ̀ fún òde ojoojúmọ́ tàbi fún ayẹyẹ, wọn ni lati wé gèlè ki imúra lè pé Fún ji jade ojoojúmọ́, a lè lo ipèlé aṣọ àdirẹ àti àwọn aṣọ igbàlódé lati fi wé gèlè, ṣùgbọ́n fún òde gidi, gèlè igbàlódé tàbi Aṣọ Òfì ti wọn npe ni Aṣọ Òkè ni Yorùbá ma nwe Eleyi jẹ ki imúra Yorùbá gbayì ni gbogbo àgbáyé Ẹ ṣe àyẹ̀wò wi wé gèlè ni ojú iwé yi Ni ayé àtijọ́, kò si ohun ti ó njẹ́ Agbalésanwó nítorí kò si ẹni ti kò ni ẹbi ti wọn lè bá gbé ni ọ̀fẹ́ Kò wọ́pọ̀ ki èniyàn kúrò ni ilé lati lọ gbé ilú miran Iṣẹ́ méjì ti ó wọ́pò ni ayé àtijọ́ ni iṣẹ́ àgbẹ̀ àti òwò nípa ti ta irè oko ni ọjọ́ Ọjà Oko lati Abúlé kan si ekeji Kò si ohun irinna bi ayé òde òni, nítorí náà ẹsẹ̀ ni wọn fi nlọ lati ilú kan si ekeji Yorùbá fẹ́ràn àlejò, nítorí eyi, bi Oníṣòwò bá lọ si Ọjà Oko ni ilú miran, ti kò lè délé ni ọjọ́ ti ó gbéra, yio ri ilé sùn ni abúlé ti ó bá dé ti ilẹ̀ fi ṣú lai sanwó Olóko ni o ma npèsè ibùgbé fún Alágbàṣe ti wọn bá gbà fún iṣẹ́ oko, nítorí eyi, kò si pé àlejò gba ilé lati sanwó Ìsọ̀ Ọjà oko Ni igbà ti ó yá, èrò bẹ̀rẹ̀ si kúrò lati ilú kan si ekeji, pàtàkì nítorí ọ̀gbẹlẹ̀, iyàn, ogun tàbi ẹni ti wọn lé kúrò ni ilú nítorí iwà burúkú Ni ayé òde òni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ má a nkúrò ni ilé lati wá iṣẹ́ lọ si ilú miran Ó rọrùn fún ẹni ti ó kàwé àti oníṣẹ́ ọwọ́ lati ri iṣẹ́ nítorí oriṣiriṣi iṣẹ́ pọ ni ilú nlá, ju ilú kékeré lọ Eleyi jẹ́ ki ilú nlá bẹ̀rẹ̀ si fẹ si Gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá Ọ̀kọ́lé kò lè mu ràjò, bẹni kò si bi ẹni ti ó kúrò ni ilé ti lè gbé ilé dáni lọ si ilú nlá Àlejò bẹ̀rẹ̀ si pọ̀ si ni ilú nlá ṣùgbọ́n ilé gbigbé kò kári Àṣà ti ó wọ́pọ̀ ni ki Onilé gba owó ọdún kan tàbi méjì Elòmìràn ngba ọdún mẹta fún owó à san silẹ̀ Ilé wá di ohun à mu ṣowó Oriṣiriṣi àwọn oniṣẹ́ Abániwálé wá pọ̀ si Ọ̀pọ̀ Onilé àti Abániwále bẹ̀rẹ̀ si lu jìbìtì nípa gbi gba owó lọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ Agbalésanwó lóri ilé kan ṣoṣo, òmíràn ngba owó lóri ilé ti ki ṣe ti wọn Yorùbá ni Alágbàtà tó nsọ ọjà di ọ̀wọn, bi ilé bá ti wọn tó ni owó ti Abániwále má a ri gbà ti pọ̀ tó Eyi jẹ́ ki wọn sọ ilé di ọ̀wọ́n, nítorí owó ti wọn má a ri gbà lọ́wọ́ Onilé àti Agbalésanwó lai ro inira Agbalésanwó Oriṣi mẹta ni Yorùbá ka igbà ẹ̀dá si Gẹ́gẹ́ bi àgbà ninú Olórin ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú Olóyè Ebenezer Obey ti kọ́ pé Igbà mẹta ni igbà ẹ̀dá láyé, igbà òwúrọ̀, igbà ọ̀sán, igbà alẹ́, ki alẹ́ san wá ju òwúrọ̀ lọ Igbà méjì ló wà fún ojú ọjọ́ – igbà òjò àti ẹ̀rùn Òjò ti fẹ́rẹ̀ kásẹ̀ kúrò ni ilẹ̀ ni oṣù kẹsan ọdún nítorí àsikò ìkórè sún mọ́lé lẹhin òjò Gẹgẹ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé Igba ó yẹ ki enia kọ lati lo àsikò dáradára, nítorí igbà kò dúró de ẹni kan Kò yẹ ki enia fi àkókò ṣòfò, nítorí ẹni kò gbin nkan, kò ni ẹ̀tọ́ àti kórè ni igbà ikórè Ọ̀rọ̀ yi ṣe rán ẹni ti ó bá nfi àárọ̀ ṣeré leti pé bi igbà bá ti lọ, kò ṣe rà padà Gẹ́gẹ́ bi a ti kọ tẹ́lẹ̀, ẹrù àti owó àna yàtọ̀ lati idilé kan si ekeji, ṣùgbọ́n àwọn ohun àdúrà bára mu ni ilẹ̀ Yorùbá pàtàkì Oyin, Obi, Ataare, Orógbó Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbi Yorùbá, ogoji ni oye àwọn ẹrù bi Obi, Orógbó, Ataare, Ẹja-gbígbẹ àti Iṣu ti idile ma ngba Olóri ẹbi lè din oye ẹrù ku lati din ìnáwó ọkọ ìyàwó kù Lẹhin igbéyàwó ibilẹ̀, wọn yio pin ẹrù yi, si ọ̀nà méjì lati kó apá kan àti apá keji fún Idilé Bàbá àti Ìyá ìyàwó yàtọ̀ si ẹrù fún ìyàwó Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ ẹrú ati owó àna fún Idilé Arinmájàgbẹ̀ ni Ìbòròpa-Àkókó, ìpínlẹ̀ Ondó ni ojú iwé yi Ọ̀rọ̀ ijinlẹ àti Òwe Yorùbá wà lati fi kọ́ ọgbọ́n àti imò bi èniyàn ti lè gbé igbésí ayé rere Ọ̀gá àgbà ninú Olórin ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú kọ ninú orin ni èdè Yorùbá pé ki lẹni kan ṣe, tẹni kan ò ṣe ri Kò si owó, ọlá, ipò, agbára ti èniyàn ni, ti kò si ẹni tó ni ri tàbi ti ẹni ti ó mbọ̀ lẹhin kò lè ni Iwájú lèrò mbá èro Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé Iwájú lèrò mbá èrò ṣe gba ẹni ti kò bá ni ìtẹ́lọ́rùn ni ìmọ̀ràn Ọjọ́ ori nlọ sókè ṣùgbọ́n ki wá lẹ̀ Ai ni ìtẹ́lọ́rùn ló fa ki àgbàlagbà jowú ọmọdé nítorí ọmọ àná ti ó rò pé kò lè da nkankan ti da nkan, tàbi ki ọ̀gá ilé-iṣẹ́ ma jowú ọmọ iṣẹ́ Bi a bá ṣe akiyesi eré ije Fi fa Okun a o ri pé àwọn kan wà ni iwájú, bẹni àwọn kan wà lẹhin Èyi fihàn pé, Ibi ti àgbà bá wà lọmọdé mba, ṣùgbọ́n àgbà ti ṣe ọmọdé ri Ai ni ìtẹ́lọ́rùn lè fà ikú ójiji nítorí àìsàn ẹ̀jẹ̀-riru, irònú, ijiyà iṣẹ́ ibi, olè jijà, ija, gbigbé oògùn olóró, èrú ṣi ṣe, àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ Bi èniyàn bá kọ́ ọgbọ́n ninú ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé Iwájú lèrò mbá èro yi, à ri pé, kò si ipò ti òhún wà ti kò si ẹni ti ó wà nibẹ̀ ṣáájú tàbi lẹhin òhun Ìmọ̀ yi kò ni jẹ́ ki èniyàn ṣi iwà hù, tàbi binú ẹni keji Ó ṣe pàtàkì gẹ́gẹ́ bi ikan ninú orin, pe Ipò ki pò, ti a lè wà, ká má a dúpẹ́ ló tọ́ Yorùbá ma nlo òwe yi nígbàtí èniyàn bá ṣẹ̀ tàbi ṣe nkan burúkú si ẹni keji, ti wọn bẹ̀rẹ̀ si bẹ ẹni ti wọn ṣẹ̀ lai mọ bóyá ẹni ti ó ṣẹ̀ ni àyipadà ọkàn kúrò ni iwà ìbàjẹ́ tàbi iṣẹ́ ibi A tún lè ṣe àpẹrẹ pé wọn mbẹ Adájọ́ ki ó ṣe àánú fún ọ̀daràn lai jẹ ki ó ronú ohun burúkú ti ó ṣe, ki ó lé yi padà Agbejọ́rò mbẹ Adájọ́ Oníṣègùn ninú òwe yi lè jẹ́, Òbi, Ọ̀gá ilé-iṣẹ́, Adájọ́, Ọlọpa, Ọ̀rẹ́, Ẹ̀gbọ́n, Àbúrò àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ, nígbàtí Aláìsàn jẹ ẹni ti ó ṣẹ̀ Lai si ìbáwí tàbi ijiyà fún ẹ̀ṣẹ̀, ẹlẹ́sẹ̀ tàbi ọ̀daràn kò ni yi padà Nítorí eyi, ó yẹ ki á bẹ alaisan, ki ó lè lo oògùn ti Oníṣègùn ṣe, ki ó bà lè ri ìwòsàn, ki wọn tó bẹ Oníṣègùn Yorùbá ma ńṣe ọdún Egúngún ni ọdọ-dún lati ṣe iranti Bàbánlá wọn ti ó ti di olóògbé nítorí wọn ni iṣẹ́ lati ṣe laarin alàyè lati rán ará ilú leti pé ki wọn di àjogúnbá ẹ̀kọ́ iwà rere mú Yorùbá má ńpe Egúngún ni Ará Ọ̀run Egúngún ma ńgbé ọ̀pá tàbi ẹgba lati na ẹni ti ó bá hu iwà burúkú ni àwùjọ Eégún ma ńgbé ọ̀pá tàbi ẹgba lati na ẹni ti ó bá hu iwà burúkú ni àwùjọ Fún àpẹrẹ, obinrin ti kò múra dáradára tàbi ẹni ti ó bá wọ bàtà, Eégún á le lati naa Òwe Yorùbá ti ó ni bi Eégún bá ńlé ni ki a má rọ́jú, bi ó ṣe ńrẹ ará ayé, ló ńrẹ ará Ọrun, ṣe gba ẹni ti ó bá wà ninú ìṣòro ni ìyànjú pé, ìṣòro yi ki ṣe ohun ti kò ni tán tàbi ni òpin Èyi tùmọ́ si pé, ìṣòro yi á ré kọjá bi enia bá lè rọ́jú Ni igbà àtijọ́, oníyàwó kan kò wọ́pọ̀ nítorí iṣẹ́ Àgbẹ̀ Àṣà fi fẹ́ ìyàwó púpọ̀ ṣe kókó nítorí bibi ọmọ púpọ̀ pàtàkì ọmọ ọkùnrin fún irànlọ́wọ́ iṣẹ́-oko Fi fẹ̀ ìyàwó púpọ̀ kò pin si ilẹ̀ Yorùbá tàbi ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú nikan, ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Aláwọ̀funfun ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin ṣùgbọ́n nítorí òwò ẹrú àti ẹ̀sin igbàgbọ́ wọn bẹ̀rẹ̀ àṣà fi fẹ ìyàwó kan Lẹhin òwò ẹrú, li lo ẹ̀rọ igbàlódé fún iṣẹ́ oko jẹ ki Aláwọ̀funfun lè dúró pẹ̀lú àṣà fi fẹ́ ìyàwó kan Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ ayé òde òni ti kọ àṣà fi fẹ́ ìyàwó púpọ̀ silẹ̀ nítorí ẹ̀sìn, ìmọ̀ àti si sá fún rògbòdiyàn ti ó lọ pẹ̀lú ìyàwó púpọ̀ Iṣẹ́ Alákọ̀wé kò ṣe fi jogún fún ọmọ nítorí iwé-ẹ̀ri àti ipò ti èniyàn dé ni iṣẹ́ Akọ̀wé tàbi iṣẹ́ Ìjọba kò ṣe fi jogún fún ọmọ bi oko Owó ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Oniṣẹ́-oṣ̀u ngba kò tó lati bọ́ ìyàwó kan ki owó oṣù míràn tó wọlé, bẹni kò tó gba ilé nla ti ó lè gba ìyàwó púpọ̀ pàtàkì ni ilú nla bi Èkó Àṣà ìyàwó púpọ̀ ṣi pọ̀, ni àwọn ilú kékeré tàbi Abúlé laarin àwọn àgbẹ̀ àti àwọn ti kò kàwé Ọmọ Oníyàwó púpọ̀ Yorùbá ni Bàbá, bàbá gbogbo ayé, bi ìyàwó kò bá ni iṣẹ́ lati tọ́jú ọmọ wọn, ìṣẹ́ dé, nítorí eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ obinrin Yorùbá ma ntẹpá mọ́ṣẹ́ lati lè tọ́jú ọmọ wọn lai dúró de ọkọ Ìyà àti ìṣẹ́ ni fún ọmọ púpọ̀ àti àwon ìyàwó ọkùnrin ti kò ni iṣẹ́ tàbi eyi ti ó ni iṣẹ́ ti kò wúlò Ewu ti ó wà ni ilé oníyàwó púpọ̀ ju ire ibẹ̀ lọ Yorùbá ni Oníyàwó kan kò mọ ẹjọ́ oníyàwó púpọ̀ da a Lára ewu wọnyi ni, ki i si ifọ̀kànbalẹ̀ nítorí ijà àti ariwo ti owú ji jẹ laarin àwọn ìyàwó ma nfà pàtàkì ni agbo ilé nlá tàbi ilé Ọlọ́rọ̀ àti Olóyè Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé oníyàwó púpọ̀ ma nda ahoro lẹhin ikú Olóri ilé nítorí kò si ẹni ti ó ni ìfẹ́ tọ si Bàbá oníyàwó púpọ̀ Kò si ilú, ẹ̀yà tàbi àwọ̀ ti kò ni ẹni burúkú tàbi ẹni rere Àti ẹni burúkú àti ẹni rere ló wà ninú ẹbi, ilú, àti gbogbo ẹ̀yà àgbáyé ninú èniyàn dúdú àti funfun, ọkùnrin, obinrin, ọmọdé àti àgbà Bi èniyàn bá pàdé ẹni kan tàbi méjì ni àkọ́kọ́, ti ó ti ẹ̀yà tàbi ilú kan jade, ti ó si hùwà rere, ni ọ̀pọ̀ igbà, ó wọ́pọ̀ lati rò wi pé gbogbo ará ilú bẹ́ ẹ̀ ló dára, ni ida keji, ti irú ẹni bẹ́ ẹ̀ ba hùwà burúkú, ó wọ́pọ̀ lati rò wi pé gbogbo ẹni ti ó ti irú ẹ̀yà yi jade ni ẹni burúkú Bi a bá tori ẹni burúkú fọ́jú, a kò ni ri ojú ri ẹni rere Ọ̀pọ̀ igbà, lai pàdé enia ri, ẹlòmiràn lè ni lọ́kàn pe ẹni burúkú tàbi ẹni rere ni ohun pàdé nítorí itàn ti ó ti gbọ́ Itàn yi lè nipá lóri irú iwà ti èniyàn yio hu si ẹni ti a bá pàdé Fún àpẹrẹ, wọn a ni Ìjẹ̀bú fẹ́ràn owó ju ẹmi lọ, Ondó njẹ Ajá, Ọ̀yọ́ ayọ́mọọ́lẹ̀, Èkìtì ni agidi, Ìjẹ̀shà – Òṣómàáló àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ Ki ṣe gbogbo àwọn ará ilú wọnyi ló bá àpèjúwe yi mu Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fọ́jú nítorí iwà burúkú ẹni kan tàbi itàn burúkú Ó wọ́pọ̀ laarin ẹbi ọkùnrin àti obinrin àfẹ́sọ́nà, ki obi kọ̀ ki wọn fẹ́ra nítorí itàn pé idilé tàbi ilú ti ikan ninú ọkùnrin tàbi obinrin ti jade kò dára Lára ewu ti ó wà ninú ki èniyàn tori ẹni burúkú fọ́jú, ọ̀pọ̀ ti tàsé ìyàwó tàbi ọkọ rere lai farabalẹ̀ wo iwà ẹni ti ọmọ wọn mú wálé tàbi tàsé ẹni rere Nítorí òwe Yorùbá ti ó sọ pé Bi a bá tori Ẹni burúkú fọ́jú, a kò ni ri ojú ri ẹni rere, ó yẹ ki a farabalẹ̀ wo iwà ẹni ti a bá pàdé ju ki itàn tàbi iwà awọn diẹ ba gbogbo ẹni ti ó bá ti ẹbi, ilú tàbi ẹ̀yà kan jẹ́, ki á lè ri ojú ri ẹni rere Ni ayé igbà kan ri ki ṣe oye ọkọ, ilé gogoro, aṣọ àti owó ni ilé-ìfowó-pamọ́ ni a fi nmọ Ọlọ́rọ̀ bi kò ṣe pé oye Ẹrú, Ìyàwó, Ọmọ, Ẹran ọsin àti oko rẹpẹtẹ ni a fi n mọ Ọlọ́rọ̀ Ni àsikò yi, Bàbá kan wa ti ó ni ìyàwó púpọ̀, Oko rẹpẹtẹ, ogún-lọ́gọ̀ ohun ọsin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ẹrú tàbi Alágbàṣe, Ọmọ púpọ̀, ṣùgbọ́n ninú gbogbo ọmọ wọnyi, ikan ṣoṣo ni ọkùnrin Bàbá fi ikan ninú gbogbo Ẹrú ti ó ti pẹ́ pẹ̀lú rẹ, ṣe Olóri fún àwọn Ẹrú yoku Ẹrú yi fẹ́ràn Bàbá, ó si fi tọkàn-tọkàn ṣe iṣẹ́ fún Nígbàtí Bàbá ti dàgbà, ó pe àwọn àgbà ẹbí lati sọ àsọtẹ́lẹ̀ bi wọn ṣe ma a pín ogún ohun lẹhin ti ohun bá kú nítorí kò si iwé-ogún bi ti ayé òde oni Ó ṣe àlàyé pé, ohun fẹ́ràn Olóri Ẹrú gidigidi nítorí o fi tọkàn-tọkàn sin ohun, nítorí náà a, ki wọn kó gbogbo ohun ini ohun fún Ẹrú yi Ó ni ohun kan ṣoṣo ni ọmọ ọkùnrin ohun ni ẹ̀tọ́ si lati mu Lẹhin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, Bàbá re ibi àgbà nrè, ó ku Lẹhin ìsìnkú, àwọn ẹbí àti àwọn ọmọ Olóògbé pé jọ lati pín ogún Ni àsikò yi, ọmọ ọkùnrin ni ó n jogún Bàbá, pàtàkì àkọ́bí ọkùnrin nítorí ohun ni Àrólé Gẹgẹ bi àsọtẹ́lẹ̀, wọn pe Olóri Ẹrú jade, wọn si ko gbogbo ohun ini Bàbá ti o di Oloogbe fún Wọn tún pe ọmọ ọkùnrin kan ṣoṣo ti Bàbá bi jade pé ó ni ẹ̀tọ́ lati mu ohun kan ti ó bá wu u ninú gbogbo ohun ini Bàbá rẹ, nítorí eyi wọn fún ni ọjọ́ meje lati ronú ohun ti ó bá wù ú jù Àwọn ẹbí sun ìpàdé si ọjọ́ keje Inú Ẹrú dùn púpọ̀ nígbàtí inú ọmọ Bàbá bàjẹ́ Eyi ya gbogbo àwọn ti ó pé jọ lẹ́nu pàtàkì ọmọ Bàbá nítorí ó rò pé Bàbá kò fẹ́ràn ohun Lẹhin ìbànújẹ́ yi, ó gbáradi, ó tọ àwọn àgbà lọ fún ìmọ̀ràn Ẹbí pé jọ lati pín Ogún Ni ọjọ́ keje, ẹbí àti ará tún péjọ lati pari ọ̀rọ̀ ogún pin-pin, wọn pe ọmọ Bàbá jade pé ki ó wá mú ohun kan ṣoṣo ti ó fẹ́ ninú ẹrù Baba rẹ Ó dide, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ti ó joko, ó yan Olóri Ẹrú gẹgẹ bi àwọn àgbà ti gba a ni ìyànjú Inú Ẹrú bàjẹ́, ṣùgbọ́n o ni ki Ẹrú má bẹ̀rù, Ẹrú na a ṣe ìlérí lati fi tọkàn-tọkàn tọ́jú ohun ti Bàbá fi silẹ̀ Idi niyì ti Yorùbá ṣe ma npa a lowe pe Ẹni tó ni Ẹrú ló ni Ẹrù Lára ẹ̀kọ́ itàn yi ni pé, ó dára lati lo ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n nítorí Ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n ni ki i jẹ ki á pe àgbà ni wèrè Ẹ̀kọ́ keji ni pé, ogún ti ó ṣe pàtàkì jù ni ki á kọ ọmọ ni ẹ̀kọ́ lati ilé àti lati bójú tó ẹ̀kọ́ ilé-iwé Bàbá, iyá àti ọmọ ni wọn mọ si Idilé ni Òkè-òkun ṣùgbọ́n ni ilẹ̀ Yorùbá kò ri bẹ́ ẹ̀, nítorí ẹbi Eg bàbá, ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ẹni, ọmọ, ọkọ àti aya wọn ni a mọ̀ si Idilé Yorùbá fẹ́ràn lati má a bọ̀wọ̀ fún àgbà nítorí eyi, ẹni ti ó bá ju Bàbá àti Ìyá ẹni lọ Bàbá tàbi Ìyá la n pè é, wọn ki pe àgbà ni orúko nítorí eyi, wọn lè fi orúkọ ọmọ pe àgbà tàbi ki wọn lo orúkọ apejuwe bi Bàbá Èkó, Iyá Ìbàdàn Ẹ ṣe à yẹ̀ wò àlàyé àti pi pè ibáṣepọ̀ idilé ni ojú iwé yi Láyé àtijọ́, iṣẹ́ Ọdẹ jẹ ikan ninú iṣẹ gidi ni ile Yorùbá Ògbójú Ọdẹ ló npa ẹranko bi Erin, Ẹkùn, Kìnìún àti Ẹfòn, Ìmàdò, nígbàtí àwọn to nṣe Ọdẹ etílé npa ẹranko ìtòsí ilé bi Ọ̀kẹ́rẹ́, Òkété, Ọ̀bọ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Ẹran ìgbẹ bi Ìgalà, Àgbọ̀nrín àti ẹran ọ̀sìn bi Àgùntàn, Ewurẹ, Òbúkọ, Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ ẹran tí o wọ́pọ̀ fún jíjẹ ni ayé àtijọ dípò ẹran màlúù tí ó wá wọpọ láyé òde òní Àwọn ẹranko bi Ẹfọ̀n, Erin, Kìnìún, Ẹkùn ti dínkù nígbàtí ẹranko bi Àgbánreré ti parẹ́ ni ilẹ̀ Yorùbá A lè fi ò̀we Yorùbá Bi Ọdẹ bá ro ìṣẹ́ ro ìyà inú igbó, ti ó bá pa ẹran kòní fẹ́nì kan jẹ wé ìyá ti àwọn ti ó wà ni Ìlúọba njẹ nínú òtútù lati pa owó Nínú owó yi, wọn a ronú àti ran àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ti wọn gbìyànjú lati ràn lọ́wọ́, ki i wo ìya ti ojú wọn rí Ẹ rántí wípé ẹni ti o bá laanu ló lè ronú lati ran ẹlòmíràn lọ́wọ́ Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ itàn Yorùbá, Ìjàpá jẹ ọ̀lẹ, òbùrẹ́wà, kò tóbi tó àwọn ẹranko yoku, ṣùgbọ́n ó ni ọgbọ́n àrékérekè ti ó fi ngbé ilé ayé Ò̀we Yorùbá sọ wi pé, Iwà jọ iwà, ni ọ̀rẹ́ jọ ọ̀rẹ́, ṣùgbọ́n ninú itàn yi, iwà Ìjàpá àti Ọ̀bọ kò jọra Ìjàpá pẹ̀lú Ọ̀bọ di ọ̀rẹ́ nítorí wọn jọ ngbé àdúgbò Gbogbo ẹranko yoku mọ̀ wi pé iwà wọn kò jọra nítorí eyi, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wọn irú ọ̀rẹ́ ti wọn bára ṣe Ọgbọ́n burúkú kó wọn Ìjàpá, ni ọjọ́ kan ó bẹ̀rẹ̀ si ṣe àdúrà lojiji pé Àkóbá , àdábá, Ọlọrun ma jẹ ká ri, Ọ̀bọ kò ṣe Àmin àdúrà nítorí ó mọ̀ wi pé kò si ẹni ti ó lè ṣe àkóbá fún Ìjàpá, à fi ti ó bá ṣe àkóbá fún elòmiràn Inú bi Ìjàpá, ó ka iwà Ọ̀bọ yi si à ri fin, ó pinu lati kọ lọ́gbọ́n pé ọgbọ́n wa ninú ki enia máà ṣe Àmin si àdúrà àwọn àgbà Ìjàpá ṣe àkàrà ti ó fi oyin din, o di sinú ewé, ó gbe tọ Ẹkùn lọ Ki Ẹkùn tó bèrè ohun ti Ìjàpá nwa lo ti gbo oorun didun ohun ti Ìjàpá Ijapa gbe wa Ìjàpá jẹ́ ki Ẹkùn játọ́ titi kó tó fún ni àkàrà olóyin jẹ Àkàrà olóyin dùn mọ́ Ẹkùn, ó ṣe iwadi bi òhun ti lè tún ri irú rẹ Ìjàpá ni àṣiri ni pé Ọ̀bọ ma nṣu di dùn, lára igbẹ́ rẹ ni òhun bù wá fún Ẹkùn Ó ni ki Ẹkùn fi ọgbọ́n tan Ọ̀bọ, ki ó si gba ni ikùn diẹ ki ó lè ṣu igbẹ́ aládùn fun Ẹkùn kò kọ́kọ́ gbàgbọ́, ó ni ọjọ́ ti òhun ti njẹ ẹran oriṣiriṣi, kò si ẹranko ti inú rẹ dùn bi eyi ti Ìjàpá gbé wá Ìjàpá ni ọ̀rẹ òhun kò fẹ́ ki ẹni kan mọ àṣiri yi Ẹkùn gbàgbọ́, nítorí ó mọ̀ wi pé ọ̀rẹ́ gidi ni Ìjàpá àti Ọ̀bọ Ẹkùn gba ikùn Ọ̀bọ Ẹkùn lúgọ de Ọ̀bọ, ó fi ọgbọ́n tan ki ó lè sún mọ́ òhun Ó gbá ikun Ọ̀bọ titi ó fi ya igbẹ́ gbi gbóná ki ó tó tu silẹ̀ Gẹ́rẹ́ ti Ẹkùn tu Ọ̀bọ silẹ̀, ó lo agbára diẹ ti ó kù lati sáré gun ori igi lọ lati gba ara lowo iku ojiji Ẹkùn tọ́ igbẹ́ Ọ̀bọ wò, inú rẹ bàjẹ́, ojú ti i pé òhun gba ọ̀rọ̀ Ìjàpá gbọ Lai pẹ, Ìjàpá ni Ọ̀bọ kọ́kọ́ ri, ó ṣe àlàyé fún ọ̀rẹ́ rẹ ohun ti ojú rẹ ri lọ́wọ́ Ẹkùn lai funra pé Ìjàpá ló fa àkóbá yi fún òhun Ìjàpá ṣe ojú àánú, ṣùgbọ́n ó padà ṣe àdúrà ti ó gbà ni ọjọ́ ti Obo kò ṣe Amin, pé ọgbọ́n wà ninú ki èniyàn máà ṣe Àmin si àdúrà àwọn àgbà Kia ni Ọ̀bọ bẹ̀rẹ̀ si ṣe Àmin lai dúró Idi ni yi ti Ọ̀bọ fi bẹ̀rẹ̀ si kólòlò ti ó ndún bi Àmin titi di ọjọ́ òni Ẹ̀kọ́ itàn yi ni pé, bi èniyàn bá mbá ọ̀rẹ́ ọlọ́gbọ́n burúkú rin, ki ó máà funra tàbi ki ó yẹra, ki o ma ba ri àkóbá Oriṣiriṣi òwe ni Yorùbá ni lati fihàn pé iwà rere ló ni ayé Iwà ni Yorùbá kàsí ni ayé àtijọ́ ju owó ti gbogbo ilú bẹ̀rẹ̀ si bọ ni ayé òde òni Fún àpẹrẹ, Yorùbá ni Ẹni bá jalè ló bọmọ jẹ́, lati gba òṣiṣẹ́ ni ìyànjú pé ki wọn tẹpámọ́ṣẹ́, ki wọn má jalè Ránti Ọmọ Ẹni ti Iwọ Nṣe - Leave a good legacy Ni ayé òde òni, owó ti dipò iwà Olóri Ijọ, Olóri ilú àti Òṣèlú ti ó ja Ijọ àti ilú ni olè ni ará ilú bẹ̀rẹ̀ si i bọ ju àwọn Olóri ti kò lo ipò lati kó owó ijọ àti ilú fún ara wọn Owó ti ó yẹ ki Olóri Ijọ fi tọ́jú aláìní, tàbi ki Òṣèlú fi pèsè ohun amáyédẹrùn bi omi mimu, ọ̀nà tó dára, ilé ìwòsàn, ilé-iwé, iná mọ̀nàmọ́ná àti bẹ ẹ bẹ ẹ lọ ni wọn kó si àpò, ti wọn nná èérún rẹ fún ijọ tàbi ará ilú ti ó bá sún mọ́ wọn Ará ilú ki ronú wi pé Alaaru tó njẹ́ búrẹ́dì, awọ ori ẹ̀ ló njẹ ti kò mọ̀ Owé Yorùbá ti ó sọ wi pé Ránti ọmọ Ẹni ti iwọ nṣe pin si ọ̀nà méjì Ni apá kan, inú ọmọ ẹni ti ó hu iwà rere ni àwùjọ á dùn lati ránti ọmọ ẹni ti ó nṣe, ṣùgbọ́n inú ọmọ Olè, apànìyàn, àjẹ́, àti oniwà burúkú yoku, kò lè dùn lati ránti ọmọ ẹni ti wọn nṣe Nítorí eyi, ki èniyàn hu iwà rere Ni ayé àtijọ́, àṣà ṣì ṣúpó wọ́pọ̀ ni Ilẹ̀ Yorùbá Obinrin ti ọkọ rẹ̀ bá kú wọn yio fi jogún gẹ́gẹ́ bi ìyàwó fún ọmọ ọkọ ọkùnrin tàbi ẹbi ọkọ ọkùnrin Eleyi wọ́pọ̀, pàtàkì ni idilé Ọba, Ìjòyè nla, Ọlọ́rọ̀ ni àwùjọ àti àgbàlagbà ti ó fẹ́ ìyàwó púpọ̀ Bi Ọba bá wàjà, Ọba titun yio ṣu gbogbo ìyàwó ti ó bá láàfin lópó Ni ayé ọ̀làjú ti òde òni, àṣà ṣì ṣúpó ti din kù púpọ̀, nítorí ẹ̀sìn àti àwọn obinrin ti ó kàwé ti ó si ni iṣẹ́ lọ́wọ́ kò ni gbà ki wọn ṣú ohun lópó fún ẹbi ọkọ ti kò ni ìfẹ́ si Ọkùnrin ni ẹbi ọkọ na a ti bẹ̀rẹ̀ si kọ àṣà ṣì ṣúpó silẹ̀ pàtàkì àwọn ti ó bá kàwé, nítorí ó ti lè ni ìyàwó tàbi ki ó ni àfẹ́sọ́nà Lai ti ẹ ni ìyàwó, ọkùnrin ẹbi ọkọ lè ma ni ìfẹ́ si ìyàwó ti ọkọ rẹ̀ kú Àṣa ṣì ṣúpó kò wọ́pọ̀ mọ laarin àwọn ti ó jade, àwọn ti ó ngbé ilú nla àti Òkè-òkun tàbi àwọn ti ó kàwé, ṣùgbọ́n ó wọ́pọ̀ laarin àwọn ti kò jade kúrò ni Abúlé àti àwọn ti kò kàwé Idilé ti ifẹ bá wà laarin ẹbi, ìyàwó pàápàá kò ni fẹ́ kúrò ni irú ẹbi bẹ́ ẹ̀ lati lọ fẹ́ ọkọ si idilé miran pàtàkì nítorí àwọn ọmọ tàbi ó dàgbà jù lati tun lọ fẹ ọkọ miran Ọmọ ọkọ tàbi ẹbi ọkọ ọkùnrin lè fi àṣà yi kẹ́wọ́ lati fẹ opó ni tipátipá, omiran lè pa ọkọ lati lè jogún ìyàwó Bi ìyàwó bá kú, wọn kò jẹ́ fi ọkọ rẹ jogún fún ẹbi ìyàwó Àsikò tó lati dáwọ́ àṣà ṣì ṣúpó dúró nítorí obinrin ki ṣe ẹrú tàbi ẹrù ti wọn njẹ mọ́ ogún Ìtàn sọ wí pé eku ni àdán tẹ́lẹ̀ ki ìjà nla tó bẹ́ sílẹ̀ laarin eku àti ẹyẹ Àdán rò wípé àwọn ẹyẹ fẹ́ bori, nítorí náà o fo lati lọ darapọ̀ mọ́ ẹyẹ lati dojú ìjà kọ àwọn ẹbi rẹ eku Eku àti ẹyẹ bínú si àdàn nítorí ìwà àgàbàgebè ti ó hu yi, wọ́n pinu lati parapọ̀ lati dojú ìjà kọ àdán Nítorí ìdí èyí ni àdán ṣe bẹ̀rẹ̀ si sá pamọ́ lati fi òkùnkùn bora ni ọ̀sán fún eku àti ẹyẹ títí di òní A lè fi ìtàn yi wé àwọn Òṣèlú tó nsa lati ẹgbẹ́ kan si ekeji nítorí ipò̀ ati agbára lati kó owó ìlú jẹ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, wọ́n ma lé eku méjì pa òfo ni Ọkùnrin ti o ni ìyàwó kan, ni àlè sita ma fara pamọ́ lati lọ sí ọ̀dọ̀ obìnrin keji ti wọ́n rò wípé́ á fún wọn ní ìgbádùn Nígbàtí ìyàwó ilé bá gbọ́, wọn a pa òfo lọdọ ìyàwó ilé, wọn a tún tẹ́ lọ́dọ̀ àlè Ẹ̀kọ́ ìtàn yí ni wípé iyè méjì kò dara, ọ̀dalẹ̀ ma mba ilẹ̀ lọ ni, nítorí náà, ojúkòkòrò kò lérè Ọmọ ki dédé rù lai ni idi Lára àwọn idi ti ọmọ lè fi rù ni àìsàn, ebi, òùngbẹ, ìṣẹ́, ai ni alabojuto, òbí olójú kòkòrò, ai ni òbí àti bẹ ẹ bẹ lọ Orilẹ̀ èdè Nàíjíríà ti jẹ gbogbo ìyà àwọn ohun ti ó lè mú ki ọmọ rù yi, lọ́wọ́ Ìjọba Ológun àti Òsèlú fún ọ̀pọ̀ ọdún Nígbàtí àwọn òbí ti ó fẹ́ràn ọmọ bi Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àti àwọn àgbà ti ó bèrè fún Ominira lọwọ Ilú-Ọba, ṣe Òsèlú, ilú kò rù, pàtàkì ọmọ Yorùbá Wọn fi ọrọ̀ ajé àti iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ìpínlẹ̀ , pèsè ohun amáyédẹrùn fún ilú, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé-iwé ọ̀fẹ́, àwọn tó jade ni ilé-iwé giga ri iṣẹ́ gidi àti pé àwọn ará ilú tẹ̀ lé òfin Eyi mú ìlọsíwájú bá ilẹ̀ Yorùbá ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú Lati igbà ti wọn ti kó ọrọ̀ ajé gbogbo ìpínlẹ̀ si abẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ti a lè pè ni Òbí ti jinà si ará ilú ti a lè pè ni Ọmọ ti rù Ojúkòkòrò àti olè ji jà Ìjọba Ológun àti Òṣèlú lábẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ti fa ebi, òùngbẹ àti àìsàn fún ará ilú Ni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n sẹhin, Olóri Òsèlu tuntun Muhammadu Buhari àti àtẹ̀lé rẹ Túndé Ìdíàgbọn ṣe Ìjọba fún ogún oṣù gẹgẹ bi Ìjọba Ológun Nígbàtí wọn gba Ìjọba lọ́wọ́ àwọn Òṣèlú ti ó ba ilú jẹ́ pẹ̀lú iwà ìbàjẹ́ ti wọn fi kó ilú si igbèsè lábẹ́ Olóri Òṣèlú Shehu Shagari, wọn fi ìkánjú ṣe idájọ́ fún àwọn tó hu iwà ibàjẹ́, eleyi jẹ ki ilú ké pé Ìjọba wọn ti le jù Ká ni ilú farabalẹ̀ ni àsikò na a, ilú ki bá ti dára si Nígbàtí Olóri-ogun Badamasi Babangida gba Ìjọba, inú ilú dùn nítorí àyè gba ará ilú lati ṣe bi wọn ti fẹ lati ri owó Eleyi jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ olówó ojiji pọ̀ si lati igbà na a titi di oni Àyè àti ni owó ojiji nípa ifi owó epo-rọ̀bì ṣòfò, ki kó owó ìpèsè ohun amáyédẹrùn jẹ, gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti iwà ìbàjẹ́, ló pa ilé-iwé giga, ilé-ìwòsàn, pàtàkì ìpèsè iná-mọ̀nàmọ́ná, ìdájọ́ àti bẹ ẹ bẹ lọ A lè lo òwe A ki i fi ọjọ́ kan bọ́ ọmọ tó rù ṣe àlàyé pé iwà ìbàjẹ́ àti ohun tò bàjẹ́ fún ọdún pi pẹ́ kò ṣe tún ṣe ni ọjọ́ kan, nítorí eyi, ki ará ilú ṣe sùúrù fún Ìjọba tuntun lati ṣe àtúnṣe lati ìbẹ̀rẹ̀ Ki Ìjọba tuntun na a mọ̀ pé Ori bi bẹ́, kọ́ ni oògùn ori fi fọ́, nítorí eyi ki wọn tẹ̀ lé òfin lati ṣe ìdájọ́ fún àwọn ti ó ba ilú jẹ́ Gbogbo olólùfẹ́ èdè àti àṣà Yorùbá ti ó tẹ̀lé wa ni àwọn ọdún ti ó kọjá, a ki yin fún ọdún tuntun ti ó wọlé Èdùmàrè á jẹ́ ki ọdún na a tura o Inú wa yio dùn ti ẹ bá lè darapọ̀ mọ́ wa lati kọ nípa àṣà ati itàn àdáyébá ni agbègbè yin ni ilẹ̀ Yorùbá fún àkọọ́lẹ̀ ki èdè àti àṣà Yorùbá ma ba parẹ́ Èdè àti Àṣà Yorùbá kò ni parẹ́ Ohun ti o jẹ èèwọ̀ tàbi òfin ni ilú kan le ma jẹ èèwọ̀ ni ilú miran ṣùgbọ́n bi èniyàn bá dé ilú, ó yẹ ki ó bọ̀wọ̀ fún àṣà àti òfin ilú Bi èniyàn bá ṣe nkan èèwọ̀, ó lè ṣé gbé ti kò bá si ẹlẹri lati ṣe àkóbá tàbi ki ó fi ẹnu ṣe àkóbá fún ara rẹ̀ Ni ilú kan ti a mọ̀ si Ayégbẹgẹ́, àwọn àlejò ọkùnrin méjì kan wa ti orúkọ wọn njẹ́ – Miòṣé àti Moṣétán Ọba ilú Ayégbẹgẹ́ kede pé èèwọ̀ ni lati jẹ ẹiyẹ Igún ni ilú wọn Akéde ṣe ikilọ̀ pé ẹni ti ó bá jẹ Igún, ikùn rẹ yio wu titi yio fi kú ni Àwọn àlejò méjì yi ṣe ìlérí pé kò si nkan ti yio ṣẹlẹ̀ ti àwon bá jẹ Igún, nítorí eyi wọn fi ojú di èèwọ̀ ilú Ayégbẹgẹ́ Miòṣé, lọ si oko, ó pa Igun, ó din láta, ó si jẹ́, ṣùgbọ́n ó pa adiẹ, ó da iyẹ́ adiẹ si ààtàn bi ẹni pé adiẹ ló jẹ Ọ̀pọ̀ ará ilú ti wọn mọ̀ pé èèwọ̀ ni lati jẹ Igún paapa, jẹ ninú rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò mọ pé Igún ni àwọn jẹ, wọn rò wi pé adiẹ ni Miòṣé fi ọ̀rọ̀ àṣiri yi sinú lai si nkan ti ó ṣe gbogbo àwọn ti ó jẹ Igún pẹ̀lú rẹ Moṣétán lọ si oko ohun na a pa Igun, ó gbe wá si ilé, ṣùgbọ́n kò jẹ́ Ó pa adiẹ dipò Igún, o din adiẹ ó jẹ ẹ, ṣùgbọ́n, ó da iyẹ́ Igún si ààtàn bi ẹni pé Igún lohun jẹ Ni ọjọ́ keji àwọn ará ilú ri iyẹ́ Igún wọn pariwo pé Moṣétán jẹ èèwọ̀, ó ni bẹni, ohun jẹ Igún Ni ọjọ́ kẹta inú Moṣétán bẹ̀rẹ̀ si i wú titi ara fi ni Nígbàtí ìnira pọ̀ fún Moṣétán, ó jẹ́wọ́ wi pé adiẹ lohun jẹ, ṣùgbọ́n wọn ko gba a gbọ pé kò jẹ Igun, titi ti ó fi ṣubú ti ó si kú Yorùbá ni Ẹnu Ayé Lẹbo, Moṣétán fi ẹnu kó bá ara rẹ̀ Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pé, àfojúdi kò dára, ó yẹ ki enia pa òfin mọ nítorí Bi a ti nṣe ni ilé wa, èèwọ̀ ibò miran Ẹni ti kò bá pa òfin mọ, á wọ ijọ̀ngbọ̀n ti ó lè fa ikú tàbi ẹ̀wọ̀n Ọdún Kérésì jẹ́ ọdún Onigbàgbọ́ lati ṣe iránti ọjọ́ ibi Jésù Olùgbàlà Ọjọ́ kẹjọ lẹhin ọdún Kérésìmesì ni ọdún tuntun Fún ayẹyẹ ọdún, kò si ìyàtọ̀ laarin Ìgbàgbọ́ àti Mùsùlùmi ni ilẹ̀ Yorùbá nítorí Yorùbá gbà wi pé Ẹni ọdún bá láyé, ó yẹ kó dúpẹ́ Ọpẹ́ ló yẹ ki èniyàn dá ju igbèsè ji jẹ lati ṣe àṣe hàn ni àsikò ọdún Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, àwọn Àgbẹ̀ á dari wálé pẹ̀lú irè oko pàtàkì iṣu Àwọn Oníṣòwò á ri ọjà tà nítorí àsikò yi ni Bàbá àti Ìyá ma nrán aṣọ ọdún fún àwọn ọmọdé àti oúnjẹ rẹpẹtẹ fún ipalẹ̀mọ́ ọdún Inú ọmọdé ma ndùn nítorí asiko yi ni wọn nse irẹsi àti pa adiẹ fún ọdún Àwọn ọmọdé á lọ lati ilé ẹbi kan si ekeji, ẹbi ti wọn lọ ki, á fún wọn ni oúnjẹ àti owó ọdún Àwọn àgbàlagbà naa ma ndá aṣọ ẹgbẹ́ fún idúpẹ́ ọdún, ṣùgbọ́n ki owó epo rọ̀bi tó gba igboro, ki ṣe aṣọ olówó nla bi ti ayé òde òni Àsikò ti olè npọ̀ si niyì pàtàkì ni ilú Èkó, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fẹ na owó ti wọn kò ni lati ṣe ọdún Ìpolówó ọjà pọ̀ ni àsikò yi ni Òkè-Òkun, nítorí eyi, ọ̀pọ̀ nlo ike-igbèsè tàbi ki wọn ya owó-èlè lati ra ọjà ti wọn kò ni owó rẹ Lẹhin ọdún, wọn a fi ọdún tuntun bẹ̀rẹ̀ si san igbèsè, nítorí eyi Ìyá àti Bàbá a ma a ti ibi iṣẹ́ kan lọ si ekeji lai ni ìsimi tàbi ri àyè àti bójú tó àwọn ọmọ Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ wi pé Ṣe bi o ti mọ ki i tẹ́ , nítorí eyi gbogbo ọmọ Yorùbá ni ilé, ni oko, ẹ ṣe bi ẹ ti mọ, ẹ ma tori odun na ọwọ́ si nkan ti ọwọ́ yin kò tó, ki ẹ ma ba a tẹ́ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Onigbàgbọ́ ayé òde oni ki i fẹ fi èdè Yorùbá kọrin ṣùgbọ́n ẹ gbọ́ bi ọmọ òyìnbó ti kọ orin àwọn Obinrin Rere ni ojú iwé yi Èkó ni olú ilú Nàíjíríà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ki àwọn Ijọba Ológun tó kó Olú Ilú Nàíjíríà lọ si Abuja ni bi ọdún mẹrinlélógún sẹhin Ki kó olú ilú kúrò ni Èkó kò din èrò ti o nwọ Èkó kù, ilú Èkó ngbòrò si ni, ṣùgbọn bi èrò ti npọ si, Ijọba àpapọ̀ kò ran Èkó lọwọ nípa ipèsè owó tó tó ni àsikò fún ohun amáyédẹrùn Sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ ọkọ Ká fi Èkó wé àwọn olú ilú yoku ni àgbáyé àti àwọn ilú nla ti omi yi ká, inira Èkó pọ̀ ju àwọn ilú wọnyi lọ Kò si iná mọ̀nàmọ́ná ti ó ṣe deede, kò si omi mimu fún ará ilú pàtàkì fún àwọn agbègbè titun Eyi ti ó burú jù ni ki èniyàn jade, kó má mọ igbà ti ó ma padà wọlé nípa li lo bi wákàti mẹ́fà tàbi ju bẹ́ ẹ̀ lọ ninú sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ ọkọ̀, nítorí ọ̀nà kò tó, bẹni kò dára, iwà-kuwà pọ̀ fún awakọ̀, ọkọ̀ àti èrò pọ̀ ju òpópó ọ̀nà lọ Bi Ijọba àpapọ̀ Nàíjíríà ti ri owó ori gbà ni Èkó ju gbogbo àwọn ilú yoku lọ tó, kò si irànlọ́wọ́ lati tú ọ̀nà Ijọba àpapọ̀ ṣe Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, Ijọba Ológun di Èkó lọ́wọ́ lati pèsè ọkọ̀ ojú irin ti ó ngbé èrò púpọ̀ ti Gómìnà Lateef Jakande bẹ̀rẹ̀ Bi Èkó ti tóbi tó, ibùdókọ òfúrufú kan ló wà lójú kan naa ni Ìkẹjà fún àwọn ti ó nlọ si gbogbo àgbáyé àti àwọn ti ó fẹ́ lọ si ilú Nàíjíríà miran Lati igbà ti Ijọba Ológun ti lé àwọn àjòjì ti ó dá ilé ọjà nla silẹ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwọn Olówó ilú kò ronú lati ṣe irú ilé ọjà bẹ́ ẹ̀ si gbogbo agbègbè Èkó fún irọ̀rùn ará ilú ju bi gbogbo ọjà nla ti kó ori jọ si Erékùṣù Èkó Àwọn nkan wọnyi àti iwà ibàjẹ́ àti ojúkòkòrò Ijọba Ológun àti Alágbádá ló sọ Èkó di aginjù laarin àwọn olú ilú àgbáyé A lérò wi pé Ijọba Òṣèlú ti àwọn ará ilú yàn fún àyipadà kúrò ninú iwà ibàjẹ́ tó gba orilẹ̀ èdè kan fún igbà pi pẹ́, yio wa àtúnṣe fún Èkó Gómìnà Akinwunmi Àmbọ̀dé ni lati wá àtúnṣe si iyà ti ojú ará ilú nri nípa gbi gbé ọkàn lé ọkọ̀ ilẹ́ fún ohun irinna nikan, nípa pi pari iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin àti ibùdókọ̀ ojú omi ti Ijọba Gómìnà Babátúndé Raji Fáṣọlá bẹ̀rẹ̀, ki wọn si ṣe kun nípa ipèsè ibùdókọ òfúrufú àti ohun amáyédẹrùn yoku Èkó kò ni bàjẹ́ o – ó bàjẹ́ ti Òwe Yorùbá ni Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pá, ṣùgbọ́n kò ri bẹ́ẹ̀ fún ẹni ti kò mọ ọbẹ̀ se Elomiran lè lo ọ̀kẹ́ àimọye owó lati fi se ọbẹ̀ kó má dùn nítorí, bi iyọ̀ ò ja, ata á pọ̀jù tàbi ki omi pọ̀jù Nitòótọ, owó ni enia ma fi lọ ra èlò ọbẹ̀ lọ́jà, ṣùgbọ́n fún ẹni ti ó mọ ọbẹ̀ se, ìwọ̀nba owó ti ó bá mú lọ si ọjà, ó lè fi ra èlò ọbẹ̀ gẹ́gẹ́ bi owó rẹ ti mọ, ki ó si se ọbẹ̀ na kó dùn Ẹ wo àwòrán àti pipè èlò ọbẹ ni abala ojú iwé yi Òwe yi ni a lè fi ṣe àpẹrẹ iṣẹ́ ribiribi ti Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú ṣe fún Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, ògúná gbongbo Òṣèlú ni ilẹ̀ Yorùbá àti fún orilẹ̀ èdè Nàíjíríà Nígbàtí Bàbá mba iṣẹ́ oselu kiri gbogbo àgbáyé, Iyá ló di ilé mú, ti ọkàn Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ fi balẹ̀ lati le fi ipò Olóri Òsèlú ṣe iṣẹ́ ribiribi ti ó ṣe Titi di ọjọ́ ikú ọkọ rẹ ni ọdún méjìdinlọ́gbọ̀n sẹhin, lẹhin igbéyàwó àádọ́ta ọdún, ó ṣe àti lẹhin fún ọkọ rẹ titi di ọjọ́ alẹ́, eyi jẹ àpẹrẹ rere fún gbogbo obinrin Ẹbi àti ará ti bẹ̀rẹ̀ si palẹ̀mọ́ fún ọjọ́ ibi ọgọrun fún Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú nígbàtí iròyin ikú rẹ jade pé iyá sùn ni ọjọ kọkàndinlógún, oṣú kẹsan ọdún Ẹgbàálemẹ́ẹdógún Ipalẹ̀mọ́ ìsìnku bẹ̀rẹ lati ṣe àṣeyẹ ikẹhin fún olóògbé dipò ayẹyẹ ọjọ́ ọgọrun ibi Olóri Òṣèlú Nàíjíríà Muhammadu Buhari pẹ̀lú àwọn àgbà Òsèlú, àwọn Ọba àti Ìjòyè, ọmọdé àti àgbà ilú dara pọ̀ pẹ̀lú ẹbi àti àwọn ọmọ Olóògbé lati ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin fún Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú Awólọ́wọ̀ ni ọjọ́ karùndinlọ́gbọ̀n, oṣù kọkanla ọdún Ẹgbàálemẹ́ẹdógún Sùn re o, ó digbà, o di gbóṣe Ilé-Ifẹ̀ tàbi Ifẹ̀ jẹ ilú àtijọ́ ti Yorùbá kà si orisun Yorùbá Lẹhin ọjọ mọ́kànlélógún ni Ilofi nígbàtí gbogbo ètùtù ti ó yẹ ki Ọba ṣe pari, Ọba Adéyẹyè Ẹniitàn, Ògúnwùsi gba Adé Aàrẹ Oduduwa ni ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kọkànlá ọdún Ẹgbàálemẹ́ẹdógún ni Òkè Ọra nibiti Bàbá Nlá Yorùbá Oduduwa ti kọ́kọ́ gba adé yi ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin Ọba Ogunwusi, Ọjaja Keji, di Ọba kọkànlélaadọta Ilé Ifẹ̀, lẹhin ti Ọba Okùnadé Sijúwadé pa ipò dà ni ọjọ́ kejidinlọgbọn, oṣù keje odun Ẹgbàálemẹ́ẹdógún Adé á pẹ́ lóri o, bàtà á pẹ́ lẹ́sẹ̀ Ni igbà àtijọ́, ẹranko ti wọn pè ni Ẹkùn jẹ alágbára ẹranko, bẹni Kìnìún si jẹ́ alágbára ẹranko Bi Kìnìún ti lágbára tó ninú igbó, bi ó bá bú ramúramù, ohun gbogbo ninú igbó á pa kẹ́kẹ́ titi dé ori ẹranko yoku Ti Ẹkùn nikan ló yàtọ̀, nítorí Ọlọrun fún ni ẹ̀bùn igbóyà, idi niyì ti a fi ńpè ni Baba Ẹranko, ti a ńpè Kìnìún ni Ọlọ́là Ijù Ni ọjọ́ kan, Ẹkùn gbéra lọ sinú igbó lati lọ wa oúnjẹ fún àwọn ọmọ rẹ, àwọn ọmọ ẹ kéré wọn kò lè yára bi iyá wọn Ó fún wọn ni imọ̀ràn pe ki wọn kó ara pọ̀ si ibi òkiti-ọ̀gán ti ohun ti lè tètè ri wọn, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù fún ohunkóhun tàbi ẹranko ti ó bá wá si sàkáni wọn Gẹgẹ bi a ṣe mọ, Kìnìún àti Ẹkùn, ọ̀gá ni onikálùkù láyé ara wọn, wọn ki ja Ibi ti Kìnìún bá wà Ẹkùn kò ni dé ibẹ̀, ibi ti Ẹkùn bá wà Kìnìún ò ni dé ibẹ̀ Nítorí èyi ni Yorùbá fi npa lowe pé Kàkà ki Kìnìún ṣe akápò Ẹkùn, onikálùkù yio má ba ọdẹ rẹ̀ lọ Lai fà ọ̀rọ̀ gùn àwọn ọmọ Ẹkùn gbọ́ igbe Kìnìún, wọn ri ti ó ré kọja, àwọn ọmọ Ẹkùn ti ẹ̀rù ba ti kò ṣe bi iyá wọn ti ṣe ìkìlọ̀, ìjáyà bá wọn, wọ́n sá Nígbàtí Ẹkùn dé ibùdó rẹ lati fún àwọn ọmọ rẹ ni ẹran jẹ, àwọn ọmọ rẹ kò pé, ṣ̀ugbọ́n àwọn ọmọ ti ijáyà bá padà wá bá iyá wọn, nigbà yi ni iyá wọn rán wọn leti ikilọ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jáyà Nítorí èyi, ohun kọ̀ wọ́n lọ́mọ Nígbàtí iyá wọn kọ̀ wọ́n lọ́mọ, wọn kò lè ṣe ọdẹ inú igbó mọ́, wọn di ẹranko tó ńrágó, ti wọn ńsin ninú ilé, to ńpa eku kiri Idi èyi ni Yorùbá fi npa ni òwe pé Ìjayà ló bá ọmọ Ẹkùn ti ó di Ológbò ti ó ńṣe ọde eku inú ilé Yorùbá ni bi wọn ti ma nṣe ìṣirò ki wọn tó bẹ̀rẹ̀ si ka ni èdè Gẹ̀ẹ́sì Akọ̀wé yi kọ ìṣirò ki ó tó bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé lọdọ ìyá rẹ̀ àgbà Nígbàtí ìyá-àgbà bá nṣe iṣẹ́ òwú Sányán lọ́wọ́, a ṣa òkúta wẹ́wẹ́ fún ọmọ-ọmọ rẹ̀ lati ṣe ìṣirò ni èdè Yorùbá Is̀irò ni èdè Yorùbá ti fẹ́ di ohun ìgbàgbé, nítorí àwọn ọmọ ayé òde òní kò rí ẹni kọ́ wọn ni ilé tàbi ilé-ìwé, nítorí náà ni a ṣe ṣe àkọọ́lẹ̀ ìṣirò yi si ojú ewé yi Yorùbá ni bi wọn ti ma a nka nkàn ki wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ si ka a ni èdè Gẹ̀ẹ́sì Ẹ ṣe àyẹ̀wò kíkà ni èdè Yorùbá ni ojú ewé yi Ni ayé àtijọ́, kò si itẹdi à lò sọnù bi ti ayé òde òni Bẹni wọn kò lo ìgò oúnjẹ lati fún ọmọ tuntun ni oúnjẹ Ri rọ ọmọ Ọwọ́ ọlọ́mọ tuntun ki kúrò ni omi nítorí omi ni wọn fi nto àgbo ti wọn nrọ ọmọ fún ìtọ́jú ọmọ tuntun Aṣọ àlòkù Bàbá, Ìyá àti ẹbi ni wọn nya si wẹ́wẹ́ lati ṣe itẹdi ọmọ nítorí kò si itẹdi à lò sọnú bi ti ayé òde òni Ọmọ tuntun a ma ya ìgbẹ́ àti ìtọ̀ tó igbà mẹwa tàbi jù bẹ́ ẹ̀ lọ ni ojúmọ́ Ọmọ ki i sùn ni ọ̀tọ̀, ẹ̀gbẹ́ ìyá ọmọ ni wọn ntẹ́ ọmọ si Lẹhin ọsẹ̀ mẹ́fà tàbi ogoji ọjọ́ tàbi ó lé kan ti wọn ti bi ọmọ, ìyá àti ọmọ lè lọ òde, ìyá á pọn ọmọ lati jáde Nítorí aṣọ ni itẹdi kò gba omi dúró, bi ọmọ bá tọ̀ tàbi ya ìgbẹ́, á yi aṣọ ìyá tàbi ẹni ti ó gbé ọmọ Kò si ẹ̀rọ ifọṣọ igbàlódé nítorí náà a, ó di dandan ki wọ́n fọ aṣọ ọmọ àti ẹni ti ó gbé ọmọ ni igbà gbogbo ni ilé ọlọ́mọ tuntun Eyi ni ó jẹ́ ki Yorùbá ma ki ẹni ti ó bá ntọ ọmọ lọ́wọ́ pé Ẹ kú ọwọ lómi nítorí ọwọ́ ki kúrò ni omi aṣọ fí fọ̀ Lati bi ogójì ọdún sẹhin, Epo-rọ̀bi nikan ni okùn ọrọ̀ ajé orilẹ̀ èdè Nàíjíríà, ó si ti pa owó ribiribi wọlé fún ilú Nígbàtí Epo-rọ̀bi bẹ̀rẹ̀ si pa owó wọlé, ará ilú kọ iṣẹ́ àgbẹ̀ àti àwọn ohun ti ilú nṣe silẹ̀ fún ifẹ́ ọjà òkèrè Àsikò Epo-rọ̀bi ni ilú fi irẹsi òkèrè dipò oriṣiriṣi oúnjẹ ilẹ̀ wa Ki ṣe eyi nikan, Ìjọba Ológun àti Òṣèlú bẹ̀rẹ̀ iwà ibàjẹ́ nípa ki kó owó ti ó yẹ ki wọn fi tún ilú ṣe jẹ Wọn ò kó owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yi dúró ni ilú, wọn nko lọ si Òkè-Òkun, eyi ló ba iná mọ̀nàmọ́ná, ilé-ìwòsàn, ilé-iwé, ọ̀nà, omi mi-mun àti ohun amáyédẹrùn yoku jẹ́ Lẹhin ti àwọn Ìjọba Ológun àti Òṣèlú fi ipò wọn ba ilú jẹ́ tán, bi ori bá fọ́ wọn, wọn á gba ọ̀nà Òkè-Òkun lọ fún ìtọ́jú, dipò ki wọn tú ile-iwé ṣe, wọn a fi owó ti wọn ji pamọ́ rán ọmọ lọ si Òkè-Òkun fún ẹ̀kọ́ ti ó yè kooro Wọn a fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ́ ra ilé nla si Òkè-Òkun, oúnjẹ àti èso ilú kò dùn lẹnu olówó, aṣọ àti ohun ti ará ilú nṣe kò dára tó, ọjà Òkè-Òkun nikan ni wọn lè fi yangàn Lai pẹ yi, àwọn Òṣèlú bẹ̀rẹ̀ si polongo pé ki ará́ ilu ra ọja ilú, ki owó Nàíjíríà lè gòkè Ki i ṣe ìyànjú burúkú ni eyi ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ kò dùn lẹ́nu olè, kì í ṣe lati ẹnu àwọn Òṣèlú ti ẹnu wọn ti fẹ si ọjà òkèrè nítorí wọn ti kó owó ilú pamọ́ si àwọn ilú Òkè-Òkun Bi a bá ṣe akiyesi, ki àṣiri tó tú ni àsikò Ìjọba tuntun, àwọn ti ilé-iṣẹ́ Agbógun ti ìwà ìbàjẹ́ tọka tàbi mú pé ó kó owó ilú jẹ jù̀, kò wọ aṣọ Òkè-Òkun Ó san ki wọn wọ aṣọ Òkè-Òkun, ju ki wọn kó owó rẹpẹtẹ ti wọn ji kó lọ si Òkè-Òkun Díẹ̀ ninú àwọn Òṣèlú ti Ilé Iṣẹ́ Agbógun ti Ìwà Ìbàjẹ́ fi ẹ̀sùn kàn Ẹ̀bẹ̀ la bẹ̀ Òṣèlú Nàíjíríà ki wọn ma pe Ajá l'Ọbọ fún ará ilú, ki wọn kó owó ilú ti wọn ji pamọ́ si Òkè-Òkun padà, ki wọn si fi àpẹrẹ rere silẹ̀ fún ará ilú nípa àyipadà kúrò ni iwà ojúkòkòrò àti olè ti wọn nfi ipò jà dúró Àyipadà Òṣèlú kúrò ninú iwà burúkú ni ó lè mú ki owó ilú kògè Nígbàtí àwọn Òṣèlú gba Ìjọba ni igbà keji lọ́wọ́ Ìjọba Ológun, inú ará ilú dùn nítorí wọn rò wi pé Ológun kò kọ iṣẹ́ Òṣèlú Ilú rò wi pé Ìjọba Alágbádá yio ni àánú ilú ju Ìjọba Ológun lọ Ó ṣe ni laanu pé fún ọdún mẹ́rìndínlógún ti Òṣèlú ti gba Ìjọba, wọn kò fi hàn pé wọn ni àánú ará ilú rárá Dipò ki wọn ronú bi nkan yio ti rọrùn fún ilú nípa ipèsè ohun amáyédẹrùn bi iná mọ̀nàmọ́ná, ilé-iwé, ilé-ìwòsàn, ojú ọ̀nà ti ó dára, òfin lati jẹ ki ilú tòrò, ṣe ni wọn bẹ̀rẹ̀ si ji owó ilú Bi ori bá fọ́ Òṣèlú, wọn á lọ si Òkè-Òkun nibiti wọn kó owó ti ó yẹ ki wọn fi tú ilé-ìwòsàn ṣe si Àwọn Òṣèlú Òkè-Òkun nfi owó Nàíjíríà tọ́jú ará ilú wọn nítorí eyi, gbogbo ọ̀dọ́ Nàíjíríà ti kò ni iṣẹ́ fẹ́ lọ si Òkè-Òkun ni ọ̀nà kọnà Ọmọ Onilù Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé Awọ kò ká Ojú ìlù, Ọmọ Onilù ni òhún fẹ́ má a sun Awọ jẹ bá ìròyìn ti ó jáde ni lọ́wọ́-lọ́wọ́, bi àwọn Òṣèlú ti bá owó ọrọ̀ ajé Nàíjíríà jẹ nípa bi wọn ti ṣe pin owó ohun ijà fún Ológun lati ra ibò Epo Rọ̀bì ni Awọ nítorí ó lé ni idá ọgọrin ti owó epo rọ̀bì kó ni owó ọrọ̀ ajé ti ilú tà si Òkè-Òkun Fún bi ọdún mẹ́ẹdógún ninú ọdún merindinlogun ti Èrò Ẹgbẹ́ Òṣèlú fi ṣe Ìjọba ki ó tó bọ lọ́wọ́ wọn ni ọdún tó kọjá, owó epo rọ̀bì lọ si òkè rẹpẹtẹ, ọrọ̀ ajé yoku pa owó wọlé Dipò ki wọn lo owó ti ó wọlé lati tú ilú ṣe, wọn bẹ̀rẹ̀ si pin owó lati fi ra owó Òkè-Òkun lati kó jade lọ ra ilé nlá si àwọn ilú wọnyi lati sá fún ilú ti wọn bàjẹ́ ni gbogbo ọ̀nà Owó epo rọ̀bì fọ́, awọ kò wá ká ojú ilú mọ́ Oníṣẹ́ Ìjoba kò ri owó-oṣ̀ù gbà déédé, àwọn ti ó fi ẹhin ti ni iṣẹ́ Ìjọba kò ri owó ifẹhinti wọn gba, owó ilú bàjẹ́, bẹni àwọn Òṣèlú bú owó oṣ́u rẹpẹtẹ fún ara wọn Eyi ti ó burú jù ni owó rẹpẹtẹ miran ti wọn bù lati ra ọkọ ti ìbọn ò lè wọ, olówó nla lati Òkè-Òkun fún Ọgọrun-le-mẹsan Aṣòfin-Àgbà Olóri Aṣòfin-Àgbà fẹ ra ọkọ̀ mẹsan fún ara rẹ nikan Àsìkò tó ki àwọn èrò ji lati bá àwọn olè wọnyi wi, nítorí àwọn Òṣèlú Òkè-Òkun nibiti wọn nkó owó ilú lọ, kò fi owó ilú wọn tọ́jú ara wọn, wọn nwọ ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ilú, àyè kò si fún wọn lati ja ilú ni olè bi ti àwọn Òṣèlú Nàíjíríà Olóri Ẹbi jẹ àkọ́bi ọkùnrin ni idilé Bi àkọ́bi bá kú, ọkùnrin ti ó bá tẹ̀le yio bọ si ipò Iṣẹ́ olóri ẹbi ni lati kó ẹbi jọ fún ìlọsíwájú ẹbi, nípa pi pari ijà, ijoko àgbà ni ibi igbéyàwó, ìsìnkú, pi pin ogún, ìsọmọ-lórúkọ, ọdún ìbílẹ̀ àti ayẹyẹ yoku Ni ayé òde òni, wọn ti fi owó dipò ipò àgbà, nítorí ki wọn tó pe olóri ẹbi ti ó wà ni ìtòsí, wọn yio pe ẹni ti ó ni owó ninú ẹbi ti ó wà ni òkèrè pàtàkì ti ó bá wà ni Èkó àti àwọn ilú nla miran tàbi Ilú-òyìnbó Ai ṣe ojúṣe Ìjọba nípa ipèsè ilé-iwòsàn ti ó péye, Ilé-iwé, omi mimu àti ohun amáyédẹrùn yoku jẹ ki iṣẹ́ pọ fún olóri ẹbi Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ wi pé Olóri Ẹbi, Baba Bùkátà, iṣẹ́ nla ni lati jẹ Olóri Ẹbi, ó gba ọgbọ́n, òye àti ìnáwó lati kó ẹbi jọ Ni ai pẹ yi, Olùkọ̀wé yi bẹ ilé wò fún bi ọ̀sẹ̀ mẹta A ṣe àwọn akiyesi wọnyi Ilú Èkó n fẹ̀ si, ṣùgbọ́n ọ̀nà kò fẹ̀ tó bi èrò àti ọkọ̀ ti pọ̀ tó, nítorí eyi, sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ kò jẹ́ ki ará ilú gbádùn Àwọn ti ó nlọ si ibi iṣẹ́ agogo mẹjọ ni lati kúrò ni ilé ki agogo marun tó lù, wọn yio si wọlé ni agogo mẹwa lẹhin ti wọn bá pari iṣẹ́ ni agogo marun Ó kéré jù, òṣìṣẹ́ yio lo wákàtí mẹfa lati lọ àti bọ ni ibi iṣẹ́ nítorí sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ Sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ Ìjọba ko ti i ṣe ìpèsè omi ẹ̀rọ, ọ̀nà àdúgbò àti ohun amáyédẹrùn igbàlódé pàtàkì ni àwọn agbègbè tuntun Iná mọ̀nàmọ́ná ti dára di ẹ̀ si, nítorí iná kò lọ púpọ̀ mọ́ bi ti tẹ́lẹ̀ Ni àwọn olú ilú ilẹ̀ Yorùbá yókù bi Ìbàdàn, Òṣogbo, Abẹ́òkúta, Àkúrẹ́ àti Adó-Èkìtì, kò si sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ bi ti Èkó ṣùgbọ́n iná mọ̀nàmọ́ná kò ṣe déédé bi ti ilú Èkó Ọ̀wọ́n epo-ọkọ̀ ti ó gbòde ni igbà ọdún Kérésìmesì ti ó kọjá àti ni ibẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun ti lọ ṣùgbọ́n epo-ọkọ̀ wọn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé epo ni àwọn olú ilú yókù ju ti Èkó Gbogbo ohun tita ló ti wọ́n si Ó ṣòro lati lo ayélujára nítorí ai ṣe déédé iná mọ̀nàmọ́ná àti ayélujára, pàtàkì bi enia ba jade kúrò ni ilú Èkó, ṣùgbọ́n ó sàn ju ti àtẹ̀hin wá lọ Ni àpapọ̀, ọyẹ́ jẹ́ ki ẹni ti ó bá nti Òkè-Òkun bọ̀ gbádùn nítorí ooru din kù Gẹgẹbi, àgbà ninu olórin Yorùbá Délé Òjó ti kọ ni ọpọlọpọ ọdún sẹhin pe Ilú òyìnbó dára, ọrẹ mi òtútù pọ̀, à ti gbọmọ lọwọ èkùrọ́ o ki ma i ṣojú bọ̀rọ̀ Àsikò òtútù ni àlejò ma ńṣe iranti ilé Òtútù ò dára fún arúgbó, a fi ti onilé náà bá lówó lati san owó iná ti o gun òkè nítorí àti tan ẹ̀rọ-amúlé gbónọ́ Ìmọ̀ràn fún àwọn ti ó gbé ìyá wọn wá si ìlú-òyìnbó, ni ki wọn gbiyànjú lati ṣe ètò fún àwọn ìyá-àgbà lati lọ si ilé ni asiko òtútù lati fara mọ́ àwọn enia wọn Òtútù o dára fún eegun àgbà Ẹ̀tẹ̀ tó mbá ilú jà ni iwà-ibàjẹ́ Ìyà ti ará ilú njẹ lọ́wọ́lọ́wọ́, ki i ṣe èrè iwà-ibàjẹ́ ọdún kan, ṣùgbọ́n ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún Kò si ìfẹ́ ilú, nítorí eyi, àwọn oniwà ibàjẹ́ ni àwọn ará ilú nyin bi wọn bá ti ẹ fi èrú kó owó jọ pàtàkì ni ilé ìjọ́sìn, wọn kò ri ẹni ba wọn wi Ojú Olé Rè é Fún akiyesi, ilé iṣẹ́ ti ó n pèsè iná mọ̀nàmọ́ná, owó ti Ìjọba àpa-pọ̀ ba pin lati pèsè iná mọ̀nàmọ́ná fún gbogbo ará ilú, ọ̀gá ilé-iṣẹ́ á pin pẹ̀lú àwọn Ìjọba Ológun tàbi Òṣèlú Alágbádá Ni bi ọgbọ̀n ọdún sẹhin, nígbàtí àwọn ọmọ iṣẹ́ ri pé àwọn ọ̀gá ti ó nji owó, kò si ẹni ti ó mú wọn, àwọn na a brẹ̀rẹ̀ si lọ yọ nkan lára ẹ̀rọ ti ó gbé iná wọ àdúgbò lati lè gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ará àdúgbò Ará àdúgbò á dá owó ki àwọn òṣiṣẹ́ ilé-iṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná tó wá tú ohun ti ó bàjẹ́ tàbi ohun ti wọn yọ ṣe Kàkà ki ará ilú para-pọ̀ lati wo ẹ̀tẹ̀ san, nípa gbi gbé ogun ti iwà-ibàjẹ́ ni ilé-iṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná, onikálùkù bẹ̀rẹ̀ si ṣètò fún ará wọn nípa ri ra ẹ̀rọ́ iná mọ̀nàmọ́ná ti àwọn òyìnbó ngbe dani nígbàtí wọn bá fẹ lọ pàgọ́ Àwọn ẹ̀rọ wọnyi kò lágbára tó lati dipò iná mọ̀nàmọ́ná ti ó yẹ ki Ìjọba pèsè Àwọn ará ilú kò ro ìnáwó ti ó kó wọn si, ariwo, àti èéfín burúkú ti ẹ̀rọ yi nfẹ sinú afẹ́fẹ́ Àwọn ti ó nja ilú lólè ni ó nkó ẹ̀rọ wọnyi wọlé, wọn kò gbèrò ki iná mọ̀nàmọ́ná wa nítorí wọn kò ni ri ẹni ra ọjà wọn Wọn rò wi pé àwọn lè dá ilé-iṣẹ́ ti ó n pèsè iná mọ̀nàmọ́ná silẹ̀ ti ó lè lo atẹ́gùn, omi, epo rọ̀bì, oòrùn lati pèsè iná ti kò léwu bi ẹ̀rọ́ iná mọ̀nàmọ́ná Ẹ̀tẹ̀ ṣòro lati wòsàn ju làpálàpá lọ, ibàjẹ́ ló yára lati ṣe ju lati tú nkan ṣe lọ O ye ki ará ilú para pọ̀ pẹ̀lú Ìjọba lọ́wọ́lọ́wọ́, lati gbé ogun ti iwà ibàjẹ́ àti àwọn aṣèbàjẹ́, ju pé ki wọn fi ara gbi gbóná kọ ìyà ọgbọ̀n ọdún laarin ọdún kan tàbi méjì Ìròyìn ti o jade ni ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹwa, oṣú karun, ọdún Ẹgbàá-le-mẹ́rìndínlógún, sọ wi pé Olóri Òṣèlú Ilú Ọba, David Cameron pe orilẹ̀ èdè Nàíjíríà ni ilú ti ó hu iwà ibàjẹ́ jù ni àgbáyé Kò ṣe àlàyé bi Ì̀jọba ilú rẹ ti ngba owó iwà ibàjẹ́ pamọ́ lati fi tú ilú wọn ṣe Ẹni gbé epo lájà, bi kò bá ri ẹni gba a pamọ́, kò ni ya lára lati tún ji omiran Bi kò ri ẹni gba a, ó lè jẹ epo na a tàbi ki ẹni tó ni epo ri mú ni wéré Gẹgẹ bi òwe Yorùbá ti sọ pé Ẹni gbé epo lájà, kò jalè̀ tó ẹni gba a, bi àwọn ti ó n fi ọna èrú àti iwà ibàjẹ́ ja ilú lólè, kò bá ri àwọn Ilú Ọba gba owó iwà ibàjẹ́ lọ́wọ́ wọn, iwá burúkú á din kù Ogun ti Ìjọba tuntun ni Nàíjíríà gbé ti iwà ibàjẹ́ lati igbà ti ará ilú ti dibò yan Ìjọba tuntun -Muhammadu Buhari àti Yẹmi Osinbajo, ni bi ọdún kan sẹhin ni lati jẹ ki àwọn tó hu iwa ibaje jẹ èrè iṣẹ́ ibi, ki wọn si gba owó iwà ibàjẹ́ padà si àpò ilú Eyi ti ó ṣe pàtàkì jù ni ki Ìjọba Ilú Ọba ṣe àlàyé bi wọn yio ti da àwon owó Nàíjíríà padà ni ipàdé gbi gbógun ti iwa ibaje, ki wọn lè fihan pé àwọn kò fi ọwọ́ si iwà ibàjẹ́ Yorùbá fẹ́ràn ayẹyẹ ṣi ṣe púpọ̀ pàtàkì fún igbéyàwó Ni ayé àtijọ́, ìnáwó igbéyàwó kò tó bi ó ti dà ni ayé òde òni Titi di bi ogoji ọdún sẹhin, ilé Bàbá ìyàwó tàbi ọgbà ẹbi ni wọn ti nṣe àpèjọ igbéyàwó Ẹbi ọ̀tún àti ti òsi yio joko fún ètò igbéyàwó lati gba ẹbi ọkọ ni àlejò fún àdúrà gbi gbà fún àwọn ọmọ ti ó nṣe igbéyàwó àti lati gbà wọn ni ìyànjú bi ó ṣe yẹ ki wọn gbé pọ̀ ni irọ̀rùn Ẹbi ọkọ yio kó ẹrù ti ẹbi ìyàwó ma ngbà fún wọn, lẹhin eyi, ẹbi ìyàwó yio pèsè oúnjẹ fún onilé àti àlejò Onilù àdúgbò lè lùlù ki wọn jó, ṣùgbọ́n kò kan dandan ki wọn lu ilu tàbi ki wọn jó Nígbàtí ìnáwó rẹpẹtẹ fún ìgbéyàwó bẹ̀rẹ̀, àwọn ẹlòmíràn bẹ̀rẹ̀ si jẹ igbèsè lati ṣe igbéyàwó pàtàkì igbéyàwó ti Olóyìnbó ti a mọ si igbéyàwó-olórùka Nítorí àṣejù yi, olè bẹ̀rẹ̀ si jà ni ibi igbéyàwó, eyi jẹ́ ki wọn gbé àpèjẹ igbéyàwó àti àwọn ayẹyẹ yoku kúrò ni ilé Wọn bẹ̀rẹ̀ si gbé àpèjẹ lọ si ọgbà ilé-iwé, ilé ìjọ́sìn tàbi ọgbà ilú àti ilé-ayẹyẹ Yorùbá fẹ́ràn ayẹyẹ ṣi ṣe púpọ̀, ṣùgbọ́n àṣà tó gbòde ni ayé òde òni, ni igbéyàwó àti ayẹyẹ bi ọjọ́ ìbí ṣi ṣe ni òkèrè Gẹgẹ bi àṣà Yorùbá, ibi ti ẹbi ìyàwó bá ngbé ni ẹbi ọkọ yio lọ lati ṣe igbéyàwó Ẹni ti kò ni ẹbi àti ará tàbi gbé ilú miran pàtàkì Òkè-Òkun, yio lọ ṣe igbéyàwó ọmọ ni òkèrè Wọn yio pe ẹbi àti ọ̀rẹ́ ti ó bá ni owó lati bá wọn lọ si irú igbéyàwó bẹ́ ẹ̀ Ẹbi ti kò bá ni owó, kò ni lè lọ nítorí kò ni ri iwé irinna gbà A ri irú igbéyàwó yi, ti ẹbi ọkọ tàbi ti ìyàwó kò lè lọ Eleyi wọ́pọ laarin àwọn Òṣèlú, Ọ̀gá Òṣìṣẹ́ Ìjọba àti àwọn ti ó ri owó ilú kó jẹ Igbéyàwó àti ayẹyẹ ṣi ṣe ni òkèrè, jẹ́ ikan ninú àṣà ti ó mba owó ilú jẹ́ Lati kúrò ni ilú ẹni lọ ṣe ìyàwó tàbi ayẹyẹ ni ilú miran, wọn ni lati ṣẹ́ náírà si owó ilu ibi ti wọn ti fẹ́ lọ ṣe ayẹyẹ, lẹhin ìnáwó iwé irinna àti ọkọ̀ òfúrufú Ilú miran ni ó njẹ èrè ìnáwó bẹ́ ẹ̀, nítorí bi wọn bá ṣe e ni ilé, èrò púpọ̀ ni yio jẹ èrè, pàtàkì Alásè àti Onilù A lérò wi pé ni àsìkò ọ̀wọ́n owó pàtàkì owó òkèrè ni ilú lati ṣe nkan gidi, ifẹ́ iná àpà fún ayẹyẹ á din kù Ìbẹ̀rù tó gbòde ayé òde òni ni pé Ayé Móoru, nítorí iṣẹ̀lẹ̀ ti o nṣẹlẹ̀ ni àgbáyé bi òjò àrọ̀ irọ̀ dá ni ilú kan, ilẹ̀-riru ni òmìràn, ọ̀gbẹlẹ̀, omíyalé, ijà iná àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ Eleyi dá ìbẹ̀rù silẹ̀ ni àgbáyé pàtàkì ni àwọn ilú Òkè-Òkun bi Àmẹ́ríkà ti ó ka àwọn iṣẹ̀lẹ̀ wọnyi si àfọwọ́fà ọmọ ẹda Wọn kilọ̀ pé bi wọn kò bá wá nkan ṣe si Ayé Móoru yi, ayé yio parẹ́ Àpẹrẹ miran ti a lè fi ṣe àlàyé pé Ọ̀run ńyabọ̀, ki ṣé ọ̀rọ̀ ẹnìkan, ni ẹni ti ó sọ pé ohun ri amin pé ayé ti fẹ parẹ́, àwọn kan gbàgbọ́, wọn bẹ̀rẹ̀ si ta ohun ìní wọn Àti ẹni ti ó ta ohun ìní àti ẹni ti ó ra, kò si ninú wọn ti ó ma mú nkankan lọ ti ayé bá parẹ ni tootọ Elòmíràn, kò ni ṣe iwadi ohun ti àwọn èniyàn fi ńsáré, ki ó tó bẹ̀rẹ̀ si sáré Ọpọlọpọ ti sa wọ inú ewu ti wọn rò wí pé àwọn sá fún Fún àpẹrẹ, nígbàtí iná ajónirun balẹ̀ ni àgọ́ Ológun ni Ikẹja ni ìlú Èkó ni bi ọdún mẹwa sẹhin Bi àwọn kan ti gbọ́ ìró iná ajónirun yi, wọn sáré titi ọpọ fi parun si inú irà ni Ejigbo ni ọ̀nà jínjìn si ibi ti ìṣẹ̀lẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ Òwe Yorùbá yi ṣe gba àwọn ti o nbẹ̀rù nigba gbogbo níyànjú wí pé ó yẹ ki èniyàn fara balẹ̀ lati ṣe iwadi ohun ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀ ki ó tó kú sílẹ̀ de ikú Bi èniyàn bẹ̀rù á kú, bi kò bẹ̀rù á kú, nítorí gẹ́gẹ́ bi itàn àdáyébá, gbogbo ohun ti ó nṣẹlẹ̀ láyé òde òni ló ti ṣẹlẹ̀ ri Àṣà Yorùbá ma ńri ọpẹ́ ninú ohun gbogbo, nítorí eyi ni àjọyọ̀ àti ayẹyẹ ṣe pọ ni ilẹ̀ Yorùbá Bi kò bá ṣe ayẹyẹ igbéyàwó, á jẹ́ idúpẹ́ fun isọmọlórúkọ, ìsìnku arúgbó, ikóyọ ninú ewu ijàmbá ọkọ̀, iṣile, oyè gbigbà ni ilé-iwé giga tàbi oyé ilú, idúpẹ́ ìparí ọdún tàbi ọdún tuntun àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Kò si igbà ti àlejò kò ni ri ibi ti wọn ti ńṣe ayẹyẹ kan tàbi èkeji ni gbogbo ilẹ́ Yorùbá Eyi jẹ́ ki àlejò rò wipé igbà gbogbo ni Yorùbá fi ńṣọdún Jijẹ, mimu ibi Igbéyàwó Kò si ẹni ti o ńdúpẹ́ ti inú rẹ ńbàjẹ́, tijó tayọ̀ ni enia fi nṣe idúpẹ́ Ninú idúpẹ́ àti àjọyọ̀ yi ni ẹni ti inu rẹ bàjẹ́ miran ti lè ni ireti pé ire ti ohun naa yio dé Ni ilú Èkó, lati Ọjọ́bọ̀ titi dé ọjọ́ Àìkú ni enia yio ri ibi ti wọn ti ńṣe ayẹyẹ Ọjọ́bọ̀ jẹ ọjọ́ ti wọn ńṣe àisùn-òkú, ọjọ́ Ẹti ni isinkú, ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ti ayẹyẹ igbéyàwó nígbàtí ọjọ́ Àìkú wà fún idúpẹ́ pàtàkì ni ilé ijọsin onigbàgbọ́ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayẹyẹ yi ló mú ipèsè jijẹ, mimu, ilù àti ijó lati ṣe àlejò fún ẹbi, ará àti ọ̀rẹ́ ti ó wá báni ṣe ayẹyẹ A lè fi òwe Yorùbá ti ó ni A ò mọ èyi ti Ọlọrun yio ṣe, kò jẹ́ ki á binú kú, tu ẹni ti ó bá ni ìrẹ̀wẹ̀sì ninú, pé ọjọ́ ọ̀la yio dára Yorùbá gbàgbọ́ pé ẹni ti kò ri jẹ loni, bi kò bá kú, ti ó tẹpá-mọ́ṣẹ́, lè di ọlọ́rọ̀ ni ọ̀la Nítorí eyi, kò yẹ ki enia Kú silẹ̀ de ikú nítorí náà, Bi ẹ̀mi bá wà, ireti ḿbẹ Ki gbogbo Nàíjíríà tó gba ominira ni àwọn Òṣèlú lábẹ́ olùdari Olóyè Ọbáfẹ́mi Awolọwọ ti fi owó kòkó àti iṣẹ́-àgbẹ̀ dá nkan ṣe fún gbogbo ilẹ̀ Yorùbá Yorùbá jẹ èrè àwọn ohun gidi, amáyé-dẹrùn bi ilé-iwé ọ̀fẹ́, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé iṣẹ́ amóhùn-máwòrán àkọ́kọ́, ilé àwọn àgbẹ̀ olókè mẹrinlélógún ilé giga àkọ́kọ́, ọ̀nà ọlọ́dà, omi, iná mọ̀nà-mọ́ná àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ Àwọn ohun ipèsè wọnyi jẹ èrè lati ọ̀dọ̀ Òṣèlú tó fẹ́ràn ilú ti ó gbé wọn dé ipò, eleyi jẹ àwò kọ́ iṣe fún àwọn Òṣèlú ẹ̀yà ilẹ̀ Nàíjíríà yókù Ìjọba Ológun fi ibọn àti ipá gbé ara wọn si ipò Òṣèlú, wọn fi ipá kó gbogbo ohun amáyé-dẹrùn si abẹ́ Ìjọba àpapọ̀ Lati igbà yi ni ilé-iwé kékeré àti giga, ilé-ìwòsàn àti ohun amáyé-dẹrùn ti Òṣèlú pèsè fún agbègbè wọn ti bẹ̀rẹ̀ si bàjẹ́ A lè fi ibàjẹ́ ohun amáyé-dẹrùn ti àwọn Òṣèlú àkọ́kọ́ pèsè fún ara ilú wọnyi wé ọbẹ̀ tó dànu,̀ ti igbẹhin rẹ já si òfò fún onilé àti àlejò Òwe Yorùbá ni Ọbẹ̀ tó dànù, òfò onilé, òfò àlejò Àpẹrẹ pàtàkì ni ọna àti ilé-iwosan ti ó bàjẹ́ Òfò ni ọ̀nà ti ó bàjẹ́ mú bá ara ilú nípa ijàmbá ọkọ̀ fún onilé àti àlejò Ibàjẹ́ ile-iwosan jẹ òfò fún onilé àti àlejò nítorí ọ̀pọ̀ àìsàn ti kò yẹ kó pani ló ńṣe ikú pani, fún àpẹrẹ, itijú ni pé, Ọba, Ìjòyè àti Òṣèlú ńkú si àjò fún àìsàn ti kò tó nkan Dákú-dáji iná mọ̀nà-mọ́ná ti ó sọ ilú si òkùnkùn jẹ́ òfò fún olówó àti aláini nítorí, yàtọ̀ si ariwo àti òórùn, ai mọye enia ni ikú ẹ̀rọ mọ̀nà-mọ́ná ti pa À ì sí Iná Mọ̀nà-mọ́ná àti Epo Ọkọ̀ bá Onílé pẹ̀lú Àlejò Ìwà ìbàjẹ́, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ló da ọbẹ̀ ohun amáyédẹrùn danu Bi ọbẹ̀ bá dànù, kò ṣe kó padà, à fi ki enia se ọbẹ̀ tuntun, bi ó bá fẹ jẹ ọbẹ̀ Yorùbá ni Ẹ̀bẹ̀ là nbẹ òṣikà, ki ó tú ilú ṣe Fún àtúnṣe, ó ṣe pàtàkì ki gbogbo ará ilú parapọ̀ lati tún ohun ti ó ti bàjẹ́ ṣe nípa gbi gbé ogun ti iwà ìbàjẹ́ àti àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà Ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ keje, oṣù kẹwa ọdún Ẹgbàálémẹ̀rindinlógún, ìròyìn pé àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ já lu ilé àwọn Adájọ́ ti wọn fi ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ kàn jade lẹhin ti wọn ti dúró titi ki Ẹgbẹ́ Adájọ́ gbé àwọn iwé ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ yẹ̀wò Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ròyìn pé wọn bá owó rẹpẹtẹ, pàtàkì oriṣiriṣi owó òkè òkun, ni ilé awon Adájọ́ wọnyi Lati igbà ti iroyin ti jade, àwọn Ẹgbẹ́ Agbẹjọ́rò lérí pé àwọn yio da iṣẹ́ silẹ̀ ti Olóri Òṣèlú Muhammadu Buhari kò bá pàṣẹ ki wọn tú àwọn Adájọ́ naa silẹ̀ ni wéréwéré Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, Adájọ́ àti Agbẹjọ́rò ki i ṣe iṣẹ́ nítorí àgbà ni ó ndá ẹjọ́ bi ijà bá bẹ́ silẹ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá Fun àpẹrẹ, bi àwọn ọmọdé bá njá, àgbàlagbà ti ó bá wà ni ilé ni yio là wọ́n, bi àwọn ìyàwó-ilé bá njà, olóri ẹbi tàbi Àrẹ̀mọ ni yio la ijà Bi ó bá jẹ́ ijà nítorí ilẹ̀ oko, Baálẹ̀ Abúlé naa ni wọn yio kó ẹjọ́ lọ bá fún idájọ́, ti ó bá jẹ àdúgbò kan si ekeji ló njà, wọn á kó ẹjọ́ lọ bá Ọba ilú àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ Lati wa idi òtitọ́, wọn lè kó àwọn ti ó njà lọ si ojúbọ Òriṣà lati búra Lẹhin ti àwọn Ìlú-Ọba pin àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilú àwọn Aláwọ̀dúdú, iṣẹ́ Agbẹjọ́rò di ki kọ́ ni ilé-iwé giga Kò si ọmọ Nàíjíríà rere ti kò mọ̀ wi pé, Ẹ̀ṣẹ̀ nlá ijiyà kékeré tàbi ki ó má si ijiyà rara fún Olówó, ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kékeré ijiyà nla ni fún tálákà tàbi aláìní, nítorí iwà burúkú àwọn Adájọ́ ti ó ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Agbejoro A ri gbọ́ wi pé bi Ọ̀gá Àgbà Agbẹjọ́rò bá ni ẹjọ́ ni iwájú Adájọ́ lẹhin ti ẹjọ́ agbejoro ti dé iwájú Adájọ́, wọn yio kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ ti Ọ̀gá Àgbà Agbẹjọ́rò gbé wá Eleyi jẹ́ ikan ninú idi pàtàkì ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Agbejoro ti fẹ́ fi ọ̀nàkọnà dé ipò Ọ̀gá Àgbà Agbẹjọ́rò Ó yẹ ki wọn gbé eyi yẹ̀wò nítorí ni ilú ti òfin bá wà, kò yẹ ki ẹnikẹni kọjá òfin Ni Òkè-Òkun, Gó́́mìnà, àgbà Òṣèlú àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ kò kọjá òfin Ẹni ma a bèrè ẹ̀tó lábẹ́ òfin yio lọ pẹ̀lú ọwọ́ mímọ́, ẹ gb́e ọ̀rọ̀ yi yẹ̀wò bóyá bi wọ́n bá fi ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ kan Adájọ́, kò yẹ ki Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ wa idi Ohun ti wọ́n bá fi ogún ọdún tàbi ju bẹ́ ẹ̀ lọ kọ́, ṣe é bàjẹ́ ni iṣéjú akàn, ṣùgbọ́n lati ṣe àtúnṣe lè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún bakan na a Ó ṣe pàtàkì ki gbogbo ọmọ ilú pinu ni ikan kan lati ṣe àtúnṣe lati bọ́ lọ́wọ́ ìnira ti ó wà ni ilú lọ́wọ́lọ́wọ́ Àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi Àyípadà tàbi Àtúnṣe yẹ ki ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òṣiṣẹ́ Ìjọba, àwọn ti ó nta ọjà, ọ̀gá ilé-iwé àti àwọn ọmọ ilé-iwé, àwọn òṣiṣẹ́ ilé-ìwòsàn, ọmọdé àti àgbà ilú Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà àti àwọn iwà ibàjẹ́ ti ó ti gbilẹ̀ fún ọdún pi pẹ́ ti ba nkan jẹ ni orilẹ̀ èdè Nàíjíríà Di ẹ ninú àwọn iwà burúkú wọnyi ni ki òṣiṣẹ́ ìjọba ji ẹrù àti owó Ìjọba fún ara wọn tàbi sọ ara wọn di alágbàtà ti o nsọ ọjà di ọ̀wọ́n nípa gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ Eleyi lo njẹ ki àwọn iṣẹ́ ti ìjọba bá gbé sita lati tú ọ̀nà ṣe, lati pèsè iná mọ̀nàmọ́ná, omi àti ohun amáyédẹrùn miran wọn ju ti gbogbo àgbáyé lọ Nítorí òṣiṣẹ́ Ìjọba ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ti ó gba iṣẹ́ lè ma ṣe iṣẹ́ tàbi ki wọn ṣe iṣẹ́ ti kò dára Ẹni ti ó nta ọjà á sọ̀rọ̀ si onibárà pẹ̀lú ẹ̀gàn, ojúkòkòrò, ìfẹ́ owó ki kó jọ ni ọ̀nà ẹ̀rú àti à ṣe hàn ló nfa iwà ibàjẹ́ àti olè jijà laarin àwọn Òṣèlú, olóri ẹ̀sìn, òṣiṣẹ́ Ìjọba, ọlọ́jà ti ó nkó ọjà pamọ́ lati fa ọ̀wọ́n, Olùkọ́ ilé iwé, ọmọ ilé-iwé kò ni itẹriba fún Olùko mọ́, àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ Ki àyipadà rere lè dé bá ilú, ó yẹ ki onikálukú yẹ ara rẹ̀ wò fún àtúnṣe kúrò ninú àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà, iwà ibàjẹ́, ai ṣojú ṣe ẹni ninú ẹbi, ai bẹ̀rù àgbà, ji ja ilú lólè, ki kó owó ilú lọ si òkèèrè, ki kọ oúnjẹ ilú ẹni silẹ̀ fún oúnjẹ òkèèrè, ayẹyẹ àṣejù, ni ná owó ti èniyàn kò gbà àti ai ni ìtẹ́lọ́rùn Ìpolongo tó nlọ lọ́wọ́ ni orilẹ́ èdè Nàíjíríà ni pé Àyípadà tàbi Àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi Yorúbà sọ wi pé Igi kan ki da a ṣe igbó, eyi túmọ̀ si wi pé ki i ṣe Olóri Ìjọba Òṣèlú àti àwọn Òṣèlú yoku nikan ni ó yẹ ki ó ṣe àtúnṣe ohun ti ó ti bàjẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣùgbọ́n gbogbo ọwọ́ ló yẹ ki ó ṣe àtúnṣe lati gbógun ti iwà ibàjẹ́ Ìjọba Ológun àkọ́kọ́ ni abẹ́ Olóògbé Ọ̀gágun Aguiyì Ironsi, da gbogbo ìpínlẹ̀ pọ si abẹ́ Ìjọba àpapọ̀ Ki wọ́n tó dá àwọn ìpínlẹ̀ pọ̀, àwọn ìpínlẹ̀ ndàgbà sókè gẹ́gẹ́ bi ohun ti ó ṣe kókó fún wọn ìpínlẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn, ti ẹ̀yà Yorùbá ngbé, ni ìgbéga ni abẹ́ Olóri Òṣèlú ìpínlẹ̀ , Olóògbé́ Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àti ẹgbẹ́ Òṣèlú rẹ Wọ́n pèsè ohun amáyédẹrùn igbàlódé bi ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé-iwé ọ̀fẹ́, ọ̀nà gidi, omi mi mun, iná mọ̀nàmọ́ná àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ ni gbogbo agbègbè ilẹ́ Yorùbá Eleyi jẹ ki Yorùbá ri ohun mu yangàn Yàtọ̀ si Ìjọba Ológun lábẹ́ Ọ̀gágun Yakubu Gowon, ti ó lo ọ̀pọ̀ owó epo rọ̀bì dáradára lati pèsè ohun amáyédẹrùn ti igbàlódé ti ilú ngbádùn titi di ọjọ́ oni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ìjọba Nàíjíríà yókù ti ó ré kọjá lábẹ́ Ológun àti Òṣèlú kùnà nípa ipèsè ohun amáyédẹrùn fún orilẹ̀ èdè nítorí iwà ibàjẹ́ Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ ti ó sọ wi pé Ni ilú afọ́jú, olójú kan lọba, laarin Ìjọba àpapọ̀, nítorí iwà-ibàjẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, a lè sọ wi pé àwọn ìpínlẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn, Èkìtì, Èkó, Ògùn, Ondó, Ọ̀ṣun àti Ọ̀yọ́ ṣe dáradára nípa ipèsè ohun amáyédẹrùn Àmọ́, ìlọsíwájú yi kò tó nkankan lára ogún ti Olóògbé Olóyè Awólọ́wọ̀ ṣe silẹ̀ Kò si ipèsè ohun amáyédẹrùn pàtàkì omi mi mun ni àwọn agbègbè tuntun lai yọ àdúgbò ọlọ́rọ̀ silẹ̀ Eleyi ló sọ gbi gbẹ́ ihò fún omi àti kànga lati wá omi fún mi mun di àṣà Àwọn ìpínlẹ̀ Yorùbá́ ti gbádùn ohun amáyédẹrùn igbàlódé fún ọjọ́ ti pẹ́, nítorí èyi ni a ṣe mbẹ̀ àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ Yorùbá pé ki wọn pèsè omi mi mun fún ará ilú gẹ́gẹ́ bi ẹ̀tọ́ lati dá àṣà gbi gbẹ́ ilẹ̀ bi ti Òkété lati wa omi ti kò ṣe e mu ni ọ̀pọ̀ igbà Yorùbá fẹ́ràn àlejò púpọ̀ Ìwà ti ọmọ ilú lè hù ti yio fa ibinú, bi àlejò bá hu irú ìwà bẹ́ ẹ̀, wọn yio ni àlejò ni, ki wọn fori ji i Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé Ojú àlejò ni a ti njẹ igbèsè, ẹhin rẹ la nsaán Eyi fi hàn bi Yorùbá ti fẹ́ràn lati ma ṣe àlejò tó Ìbàdàn ni olú-ilú ìpínlẹ̀ Yorùbá ni Ìwọ̀-Oorun Nàíjíríà tẹ́lẹ̀ ki Ìjọba Ológun ti Aguiyì Ironsi ti jẹ Olóri tó kó gbogbo ìpínlẹ̀ Nàíjíríà pọ si aarin lẹhin ti wọn fi ibọn gba Ìjọba lọ́wọ́ Òṣèlú ni aadọta ọdún sẹhin Lẹhin oṣù keje ni aadọta ọdún sẹhin, àwọn Ológun fi ibọn gba Ìjọba ni igbà keji Ti àkọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ nígbàtí wọn fi ibọn lé àwọn Òṣèlú àkọ́kọ́ lẹhin òmìnira kúrò ni ọjọ́ karùndinlógún, oṣù kini ọdún Ẹdẹgbaalemẹrindinlaadọrin Lẹhin oṣù meje, àwọn Ológun tún fi ibọn gbà Ìjọba lọ́wọ́ àwọn Ológun ti wọn fi ibọn gbé wọlé ti Aguiyì Ironsi jẹ olóri rẹ Lára Ìjọba Ológun àkọ́kọ ti Ọ̀gágun Aguiyì Ironsi ti jẹ́ Olóri Ìjọba ni wọn ti fi Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi jẹ Olóri ni ìpínlẹ̀ Yorùbá dipò Òṣèlú Ládòkè Akintọ́lá ti àwọn Ológun pa Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi gba Olóri-ogun Aguiyì Ironsi ni àlejò ni ibùgbé Ìjọba ni Ìbàdàn nígbàtí àwọn Ológun dé lati fi ibọn gba Ìjọba ni igbà keji Nígbàtí àwọn Ajagun dé lati gbé Olóri Ogun Aguiyì Ironsi lọ, gẹ́gẹ́ bi àṣà Yorùbá, Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi bẹ̀bẹ̀ ki wọn fi àlejò òhun silẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kọ Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi fi ara rẹ ji pé ti wọn ba ma a gbee, ki wọn gbé òhun pẹ̀lú Nítorí eyi àwọn Ológun gbe pẹ̀lú àlejò rẹ wọn si pa wọ́n pọ ni Ìbàdàn Ni ọjọ́ kọkandinlọgbọn oṣù keje ọdún Ẹgbàálémẹ́rindinlógún, ilú péjọ pẹ̀lú ẹbi àti ará ni Adó-Èkìtì lati ṣe iranti Olóògbé Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi fún iranti iwà iṣòótọ ti ó hù titi dé ojú ikú pẹ̀lú àlejò àti ọ̀gá rẹ Olóri Ogun Aguiyì Ironsi ni aadọta ọdún sẹhin Ikú àwọn ọkùnrin Aláwọ̀-dúdú ni ọwọ́ Ọlọpa ni orilẹ̀ èdè Àméríkà pọ̀ ju pi pa àwọn aláwọ̀ funfun tàbi laarin àwọn ẹ̀yà kékeré miran Ọ̀sẹ̀ kini oṣù keje ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún ṣòro fún àwọn Àméríkà Ìròyìn bi Ọlọpa funfun ti yin ibọn si ọkùnrin Aláwọ̀-dúdú ni ojú ọmọ àti aya nlọ lọ́wọ́ nígbàtí ìròyìn bi Ọlọpa funfun ti pa okunrin Aláwọ̀-dúdú miran bi ẹni pa ẹran ti tún jáde Àwọn iroyin yi bi àwọn èrò ninú, nítorí èyi, aláwọ̀ dúdú àti funfun tú jáde lati fi ẹ̀dùn hàn pé Ìgbésí Ayé Aláwọ̀-dúdú ṣe pàtàkì pé àwọ lè yàtọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ kò yàtọ̀ Ó ṣe ni laanu pé Micah Johnson ọkùnrin Aláwọ̀-dúdú, jagunjagun fun orile ede Àméríkà, ló pa Ọlọpa marun, ó si ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ léṣe nípa gbi gbé òfin si ọwọ́ ara rẹ pẹ̀lú ibinu Ìwà burúkú ti di ẹ̀ ninú àwọn Ọlọpa funfun yi hu ki ṣe ìwà ti ó wọ́pọ̀ laarin ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọlọpa aláwọ̀ funfun tàbi gbogbo Ọlọpa ti wọn nṣe iṣẹ́ ribiribi lati dá àbò bo àwọn ará ilú Ó ṣe ni laanu pé àwọn Aláwọ̀-dúdú ni Ọlọpa nda dúró jù ni ojú ọ̀nà ọkọ̀, ti ó dẹ̀ n kú ni irú idá dúró bẹ́ ẹ̀ Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, onidajọ ọ̀daràn kò ṣe idájọ òdodo fún Aláwọ̀-dúdú, èyi kò ran nkan lọ́wọ́ A lérò wi pé àwọn oníwà ìbàjẹ́ ti ó jẹ́ Olóri Òṣèlú ilẹ̀ Alawo dudu ti ó n ja ilú lólè lati kó irú, ọrọ̀ ilú lọ pamọ́ si àwọn ilú ti o ti dàgbà sókè yio ronú pìwàdà Èrò ti ó n kú ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú nítorí ọ̀nà ti kò dára, a i si ilé-ìwòsàn gidi, a i ni ohun amáyédẹrùn bi omi, iná mọ̀nàmọ́ná kò jẹ ki Aláwọ̀-dúdú Àméríkà lè fi orisun wọn yangàn Ni Ìlú-Ọba, lẹhin ọdún mẹtalelogoji, èrò jade lati di ìbò bẹni-bẹ́ẹ̀kọ́ lori àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ Ìlú-òyìnbó méjìdinlọ́gbọ̀n ni Ọjọ́bọ̀, oṣu Kẹfa, ọdún Egbàálémẹẹdógún Idibò na a lọ wẹ́rẹ́ lai si ìjà, kò gbà ju ìṣéjú kan si méjì lọ lati wọlé dibò ti ó bẹ̀rẹ̀ ni agogo meje àárọ̀ titi di aago mẹwa alẹ́ Lẹhin idibò, ni òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ keji idibò, ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ kẹrinlélógún, oṣù kẹfa, èsi ibò jade pé ibò bẹ́ẹ̀kọ́ ju ibò bẹni lọ, eyi ti ó túmọ̀ si wi pé, ará ilú ti ó fẹ́ ki wọn kúrò ni ẹgbẹ́ Ilú-òyìnbó pọ̀ ju àwọn ti wọn ó fẹ́ ki wọn dúró ninú ẹgbẹ́ Bi èsì ibò ti jade, Olóri Òṣèlú Ilú-Ọba, David Cameron, jade lati bá ará ilú sọ̀rọ̀ Ninú ọ̀rọ̀ rẹ, ó ni nítorí ohun polongo ki wọn dúró ninú ẹgbẹ́ Ilú-òyìnbó ṣùgbọ́n àwọn aráilú ti sọ̀rọ̀ wi pé ki wọn kúrò, nítorí eyi ohun yio gbé Ijọba silẹ̀ Ẹ̀kọ́ fún Ìjọba tiwa ntiwa ni orilẹ̀ èdè Nàíjíríà ni wi pé iwá ibàjẹ́ ti àwọn Òṣèlú nhu ni Àbùjá lai fi eti si ará ilú pé àwọn ẹ̀yà mẹ́yà orilẹ̀ èdè Nàíjíríà fẹ́ dá Ìjọba wọn ṣe ju ki Òṣèlú joko si Àbùjá lati maa na owó gbogbo ará ilú Ó yẹ ki wọn ronú bi wọn yio ti ṣe Ìjọba ti yio mu irọ̀rùn ba gbogbo ìpínlẹ̀ Nàíjíríà Ki wọn fi eti si ohun ti ará ilú lati Guusu dé Àriwá sọ, pé ki wọn joko sọ̀rọ̀ bi wọn yio ti ma bára gbé Igbe àwọn Igbo ti pọ si lẹhin ti wọn jagun abẹ́lé, àwọn ẹya miran bi Yorùbá nkun ni abẹ́lẹ̀ pé àwọn ma fẹ dá dúró ki wọn san iṣákọ́lẹ̀ fún Ìjọba àpapọ̀ Ó yẹ ki Òṣèlú Nàíjíríà ṣe àyẹ̀wò òfin ti aṣojú Ilú Ọba – Lugard fi da Guusu àti Àríwá pọ fún irọ̀rùn ìṣàkóso orilẹ̀ èdè Nàíjíríà ni ọgọrunleméjì ọdún sẹhin Nàíjíríà gba Òmìnira ni bi ọdún mẹrindinlọgọta sẹhin Lẹhin Òmìnira, àwọn Òṣèlú pàtàkì ni Ìwọ̀-oòrùn lábẹ́ Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ fi ipò Òṣèlú ṣe iṣẹ́ ribiribi lati jẹ́ ki àwọn ará ilú jẹ èrè Òmìnira, ṣùgbọ́n lati igbà ti Ìjọba Ológun ti ó fi ibọn gba Ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ si ṣe Òṣèlú ni ilú ti bàjẹ́ si, wọn si rò wi pé àwọn lé fi ipá kó orilẹ̀ èdè pọ Lati ọjọ́ ti aláyé ti dá ayé ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ti wà Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú kún fún ọrọ̀ oriṣiriṣi, ṣùgbọ́n, iwà àpà, ojúkòkòrò, ki kó ti ilé dà si ita, àti ìfẹ́ àjòjì ju ara ilé ẹni lọ, ló fa iṣẹ́ ti ó pọ̀ ni Ilẹ̀-Aláwọ̀dúdú Iwà burúkú wọnyi, pàtàkì laarin àwọn Olóri ilú tàbi alágbára ló fa ti ta ara ẹni lẹ́rú si Òkè-Òkun, ogun abẹ́lé àti òwò ẹrú ti ayé òde òni ṣi wà Àwọn Òṣèlú àti Olóri ilú kò ti kọ́ ọgbọ́n, nítorí wọn nṣe àṣiṣe si nípa li lo iṣẹ ti wọn gbà lai ṣe kó owó ilú jẹ, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti iwà ibàjẹ́ ló fa ibàjẹ́ ohun amáyédẹrùn àti ìṣẹ́ laarin ọrọ̀ ni orilẹ̀ èdè Nàíjíríà Melo ninú ọmọ ayé òde òni ló ránti àwọn Ọlọ́rọ̀ ilẹ̀ Yorùbá ni aadọta ọdún sẹhin Òmíràn kò mọ itumọ̀ ọ̀rọ̀ Èkó pé Bi ó ti ẹ lówó bi Da Rocha lai bèrè pé tani Da Rocha Àwọn Ọlọ́rọ̀ àná bi Candido Joao Da Rocha, Ọlọ́rọ̀ owó ọ̀kẹ́ aimoye àkọ́kọ́ ni orilẹ̀ èdè Nàíjíríà ti ilú Èkó, Olóyè Adéọlá Odùtọ́lá ọ̀gá Oníṣòwò ti Ìjẹ̀bú-Òde ti ìpínlẹ̀ Ògùn, Oloye Àjàó, S. Bọlaji Bakare, I.O. Àjànàkú Iléṣà, Olóyè T.A. Oni ati àwọn ọmọ-kunrin rẹ ni Ìbàdàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Oṣinọwọ oníṣòwò ọkọ̀ irinna ni Èkó, Mobọ́láji Bank-Anthony, Asábọ́rọ̀, ọmọ Ìkárọ̀ ni ẹ̀gbẹ́ Ọ̀wọ̀ ni ìpínlẹ̀ Ondo àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ ti wọn ti gbàgbé wọn pẹ̀lú ọrọ̀ ti wọn fi silẹ̀ Àwọn ti wọn ránti, ki ṣe nítorí ọrọ̀ ti wọn fi silẹ̀ láyé ni èrò ránti ṣùgbọ́n àwọn ọmọ tó gba ẹ̀kọ́ ni ó lè jẹ ki wọn ṣe iránti wọn àti bi wọn ti lo ọrọ̀ na a fún lati ṣe oore fún àwọn aláìní Àwọn Ọlọ́rọ̀ Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú kò kọ́ ọgbọ́n ninú itàn igbẹhin Ọba àti Ìjòyè ti kò lo ipò wọn dáradára, àwọn ti ó fi èrú kó ọrọ̀ jọ, tàbi ti ó lo ipò wọn lati fi tẹ ará ilú mọ́lẹ̀ ni àtijọ́ Irú ọrọ̀ bẹ́ ẹ̀ kò bá wọn kalẹ́ bẹni ìrántí wọn kò dára Ni ọjọ́ keji ọ̀sẹ̀, ọjọ́ keje oṣù kẹfà, ọdún Ẹgbàá-lémẹ́rìndínlógún, ilé-iṣẹ́ Amóhùn-máwòrán Kẹrin ni Ilú-Ọba fi àpẹrẹ hàn bi àwọn ọmọ Ọlọ́rọ̀ lati Nàíjíríà ti mba owó ninú jẹ́ ni Ilú-Ọba Yorùbá ni Ohun ti a kò bá jiyà fún, ki i lè tọ́jọ́ Wọn nná owó ti ọgọrun enia lè ná ni ọdún kan ni alẹ́ ọjọ́ kan lai ronú ọ̀pọ̀ aláìní ni orílẹ̀ èdè wọn, ti Bàbá wọn ti fa ijiyà fún lati kó ọrọ̀ ti wọn nná dànù jọ Kò si ìyàlẹ́nu ni irú iwà ti àwọn ọmọ ọlọ́rọ̀ Nàíjíríà wọnyi hù nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn bàjẹ́, wọn kò ni ẹ̀kọ́, wọn kò mọ iyì owó nítorí wọn kò ṣiṣẹ́ fun Ọbabinrin Elizabeth Keji, pé aadọrun ọdún láyé ni ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kẹrin ọdún Ẹgbàálémẹrindinlólgún Gbogbo ará ilú àti àwọn Ìjọ Onigbàgbọ́ pé jọ lati ṣe ayẹyẹ à ṣe pọ̀ fún Ọbabinrin ni ọjọ́ Ìsimi, ọjọ́ kejila, oṣù kẹfà ọdún Eleyi bọ si àsikò ti ọkọ rẹ Philips pé ọgọrundinmarun ọdún Lẹhin ti Ọbabinrin Elizabeth keji gun ori oyè ni ọdún mẹtalelọgọta sẹhin, ó bẹ ilú Èkó wò ni ọgọta ọdún sẹhin, nígbàtí Ilú Èkó jẹ́ Olú-Ilú orilẹ̀ èdè Nàíjíríà ki a tó gba Òminira lábẹ́ Ilú-Ọba ni odun Ẹdẹgbaalelọgọta A ṣe yi ṣe àmọ́dún o Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán wọnyi Ìjọba-àpapọ̀ sọ Èkó di ìpínlẹ̀ ni àádọ́ta ọdún sẹhin Èkó jẹ́ olú ilú fún gbogbo orilẹ̀ èdè Nàíjíríà tẹ́lẹ̀ ki wọn tó gbe lọ si Abuja Ìpínlẹ̀ Èkó jẹ ikan ninú ìpínlẹ̀ mẹ́fà Yorùbá Yorùbá ni Èkó gba olè, ó gba ọlẹ, ọ̀rọ̀ yi jẹ wi pé kò si irú ẹni ti ko si ni ìpínlẹ̀ Èkó nítorí Èkó gba olówó, ó si gba aláini àti wi pé iṣẹ́ pọ̀ ni Èkó ju gbogbo ìpínlẹ̀ yoku lo Kò si ẹ̀yà tàbi ẹ̀sìn Nàíjíríà ti kò si ni Èkó Nítorí èyi èrò pọ̀ jù ilẹ̀ lọ nítorí omi ló yi Èkó ká Èkó ṣe àjọ̀dún lóri agbami Àwọn Gómìnà ti ó ti jẹ lati ìgbà ti wọn ti dá ìpínlẹ̀ Èkó silẹ̀ ni wọnyi Ìnáwó rẹpẹtẹ ni ìsìnkú arúgbó jẹ́ ni ilé Yorùbá Bi arúgbó bá kú ni ilé Yorùbá ki ṣe òkú ọ̀fọ̀ ṣùgbọ́n òkú ijọ àti ji jẹ, mi mu ni pàtàkì bi irú arúgbó bá bi àwọn ọmọ ti ó ti dàgbà Gbogbo ẹbi, ará àti ilú yi ó parapọ̀ lati ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin fún irú arúgbó bẹ́ ẹ̀ Àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ yi o ṣe oriṣiriṣi ẹ̀yẹ ìbílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ lati gbé ìyá tàbi àgbà bàbá àgbà relé Bi eléré ìbílẹ̀ kan ti nlọ ni òmíràn yio de, eleyi lo njẹ́ ki ilú kékeré dùn A o ṣe àpẹrẹ àṣà ìsìnkú ìbílẹ̀ fún arúgbó pẹ̀lú ni Ìbòròpa Àkókó ilú Yorùbá ni ẹ̀gbẹ́ Ìkàrẹ́-Àkókó ti ìpínlẹ̀ Ondo, orilẹ̀ èdè Nàíjíríà Oríkì jẹ ọ̀rọ̀ ìwúrí ti Yorùbá ma nlò lati fi sọ ìtàn àṣà àti ìṣe ìdílé lati ìran dé ìran Ninú oríkì ni a ti lè mọ ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ẹbí ẹni àti ohun ti a mọ ìdílé mọ́, bí i irú iṣẹ ti wọn nṣe ni ìdílé, oriṣiriṣi èdè ìbílẹ̀ Yorùbá, oúnjẹ ti wọn njẹ àti èyí ti wọn ki i jẹ, ẹ̀sìn ìdílé, àdúgbò ti wọ́n tẹ̀dó si tàbi ìlú ti a ti ṣẹ̀ wá, àṣeyọrí ti wọn ti ṣe ni ìran ẹni àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ Ni inú oríkì ti a ó bẹ̀rẹ̀ si i kọ, a ó ri àpẹrẹ ohun ti Yorùbá ṣe ma a nsọ oríkì pàtàkì fún iwuri nígbàtí ọkùnrin, obinrin, ọmọdé àti ẹbí ẹni bá ṣe ohun rere bi ìṣílé, ìgbéyàwó, àṣeyorí ni ilé-iwé, oyè jijẹ tàbi ni ayé òde òni, àjọyọ̀ ọjọ́ ìbí Oríkì jẹ ikan ninú àṣà Yorùbá ti ó ti nparẹ́, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá bẹ̀rẹ̀ si kọ èdè àti àṣà wọn sílẹ̀ fún èdè Gẹ̀ẹ́sí Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ oríkì ti ìyá Olùkọ̀wé yi sọ fún ni ibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ ni ojú ìwé yi A ó bẹ̀rẹ̀ si kọ oríkì oriṣiriṣi ìdílé Yorùbá Ọmọ ẹlẹ́ja ò tú mù kẹkẹ Ọmọ a mẹ́ja yan ẹja Ọmọ ò sùn mẹ́gbẹ̀wá ti dọ̀ ara rẹ̀ Ọmọ gbàsè gbàsè kẹ́ ṣọbinrin lọyin Ọmọ kai, eó gbé si yàn ún Ọmọ a mú gbìrín eó b'ọ̀dìdẹ̀ Ìṣò mó bọ, òwíyé wàarè Ọmọ adáṣọ bù á lẹ̀ jẹ Ọmọ a má bẹ̀rẹ̀ gúnyán k'àdó gbèrìgbè mọ mọ̀ Ọmọ a yan eó meka run Ọmọ a mẹ́ kìka kàn yan ẹsinsun t'ọrẹ É e ṣojú un ríro, ìṣẹ̀dálẹ̀ rin ni Ọmọ a mi malu ṣ'ọdún ìgbàgbọ́ Ọmọ elési a gbàrùnbọ̀ morun Ọmọ elési a gbàdá mo yóko Èsì li sunkún ètìtù kọ gbà àrán bora li Gèsan Ọba Ọmọ Olígèsan òròrò bílẹ̀ Ọmọ alábùṣọrọ̀, a múṣu mọdi Àbùṣọrọ̀ lu lé uṣu, mọ́ m'ẹ́ùrà kàn kàn dé bẹ̀ Kare o Lúàmi, ku ọdún oni o, è í ra ṣàṣe mọ ri a. Àṣẹ Ni ìgbà àtijọ́, ọkùnrin kan wa ti orúkọ rẹ njẹ́ Ìgbéraga Wọ́n bi Ìgbéraga si ilé olórogún, àwọn ìyàwó bàbá́ rẹ yoku ni ó tọ nítorí ìyá rẹ kú nígbàtí ó wà ni kékeré Lẹhin ti o tiraka lati pari iwé mẹ́fà, gẹ́gẹ́ bi ọ̀dọ́, ó gbéra lọ si ilú Èkó nibiti ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ Ẹlẹ́ja Ó nṣe dáradára ni ibi iṣẹ́ ki ó tó gbọ́ ìròyìn ikú bàbá rẹ Ìgbéraga pinu lati padà si ilú rẹ lati gba ogún ti ó tọ́ si lára oko kòkó rẹpẹtẹ ti bàbá rẹ fi silẹ̀ Ohun fúnra rẹ ra oko kún oko bàbá rẹ ti wọn pín fun Ó di ẹni ti ó ri ṣe ju àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku Eyi jẹ ki gbogbo àwọn ọbàkan rẹ gbójú le fún ìrànlọ́wọ́ Ni igbà ti ó yá, o ni ilé àti ọlà ju gbogbo àwọn yoku ni abúlé ṣùgbọ́n kò to, ó bẹ̀rẹ̀ si ra oko si titi dé oko àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku Eyi jẹ́ ki ó sọ àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku di alágbàṣe ni oko ti wọn jogún Inú àwọn ọmọ bàbá rẹ wọnyi kò dùn si wi pé wọn ti di atọrọjẹ àti alágbàṣe fún àbúrò wọn ninú ilé ara wọn Yorùbá ni Àṣejù Baba Àṣetẹ́ Ìgbéraga bẹ̀rẹ̀ si ṣe àṣejù, kò dúró lati má a fi ọrọ̀ rẹ yangà si gbogbo ará ilú pàtàkì si àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, ó jọ ara rẹ lójú, ó si nsọ ọ̀rọ̀ lai ronú tàbi gba ikilọ̀ àwọn àgbà ti wọn mọ ìbẹ̀rẹ̀ rẹ Kò mọ̀ wi pé ohun ngbẹ́ ikòtò ìṣubú fún ara rẹ́ Ni ọjọ́ kan, ó pe ọ̀kan ninú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ti ó sọ di alágbàṣe ninú oko rẹ tẹ́lẹ̀ ó si bu, ó pe e ni aláìní dé ojú rẹ Ẹ̀gbọ́n ké pẹ̀lú omijé lójú pé Bi ó bá jẹ ìwọ ni Ọlọrun, ma ṣe iwà burúkú yi lọ, ṣùgbọ́n bi ó bá jẹ́ enia bi ti òhun, wà á ká ohun ti o gbin yi Alágbàṣe ni oko Kòkó ti wọn jogún Ni àárọ̀ ọjọ́ kan, Ìgbéraga ji ṣùgbọ́n kò lè di de nítorí ó ti yarọ Wọ́n gbe kiri titi fún itọ́jú ṣùgbọ́n asán ló já si Ìṣòro yi jẹ ki ó ta gbogbo ohun ini rẹ ti ó fi nyangàn titi o fi di atọrọjẹ Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pe àṣejù ohunkóhun kò dára pàtàkì ki enia gbójúlé ọrọ̀ ilé ayé bi ẹni pé àwọn ti ó kù kò mọ̀ ọ́ ṣe, nítorí Yorùbá sọ wi pé kìtà kìtà kò mọ́là, Ká ṣiṣẹ́ bi ẹrú kò da nkan, Ọlọrun ló ngbé ni ga Iṣẹ́ ni oògùn ìṣẹ́, múra si iṣẹ́ rẹ ọ̀rẹ́ mi, iṣẹ́ ni a fi i di ẹni gíga Bí a kò bá rẹ́ni fẹ̀hìn tì, bí ọ̀lẹ là á rí Bí a kò bá rẹ́ni gbẹ́kẹ̀lé, à á tẹra mọ iṣẹ́ ẹni Ìyá rẹ lè lówó lọ́wọ́, Bàbá si lè lẹ́ṣin leekan Bí o bá́ gbójú lé wọn, o tẹ́ tán ni mo sọ fún ọ Ohun ti a kò bá jìyà fún kì í lè tọ́jọ́ Ohun ti á fara ṣiṣẹ́ fún ní í pẹ́ lọ́wọ́ ẹni Apá lará, ìgunpá niyèkan Bí ayé n fẹ́ ọ loni, bí o bá lówó lọ́wọ́, ni wọn má a fẹ́ ọ lọla Tàbí tí o bá wà ní ipò àtàtà, ayé a yẹ́ ọ sí tẹ̀rín-tẹ̀rín Jẹ́ kí o di ẹni n rágó, kí o ri bí ayé ti n yínmú sí ọ Ẹ̀kọ́ sì tún n sọni dọ̀gá, mú́ra kí o kọ dáradára Bí o sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, tí wọn fi ẹ̀kọ́ ṣe ẹ̀rín rín Dákun má ṣe fara wé wọn Ìyà n bọ̀ fọ́mọ tí kò gbọ́n, ẹkún n bẹ fọ́mọ tó n sá kiri Má fòwúrọ̀ ṣeré, ọ̀rẹ́ mi, múra sí iṣẹ́ ọjọ́ n lọ Ẹ kú àsikò yi o Bawo ni ipalẹ̀mọ́ ọdún Kérésìmesì àti ọdún titun Ni àsikò ọdún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ma nfi oúnjẹ àjẹ jù àti ọti à mu para yọ ayọ̀ ọdún Ni òtitọ́, ará ilú nké pé kò si owó àti ọ̀wọ́n ọjà, nítorí eyi ayé àjẹ jù le ma si, ṣùgbọ́n bi ẹlòmíràn kò ni owó, á gba àwin ọti pé àwọn fẹ́ fi pa irònú rẹ́ Àwọn miran nlo egbò igi olóró ti á gbọ́ wi pé ó ti wọ́pọ̀ ni orilẹ̀ èdè Nàíjíríà pàtàkì laarin àwọn ọ̀dọ́ À fọwọ́ fà ni gbogbo eyi Kò si ìyàtọ̀ laarin ọlọ́tí pẹ̀lú ẹni ti ó mu egbò igi olóró àti wèrè, nítorí ihùwà ọlọ́ti àti ẹni lo oògùn olóró kò yàtọ̀ si ti wèrè bi wọn bá ti yó Bi ẹni ti ó mu àmu para àti ẹni lo egbò igi olóró bá wa ọkọ̀, àkóbá ni fún àwọn awakọ̀ yoku àti àwọn arin nà yoku Ki ọdún titun lè bá wa láyọ̀, ikilọ ni àsikò yi ni wi pé Ki ẹni bá mú ọti tàbi ẹni tó lo egbò igi olóró ma ṣe wa ọkọ̀ Ẹ kú ipalẹ̀mọ́ ọdún o Bi ọdún bá sún mọ́ etílé, oúnjẹ àti ohun èlò gbogbo maa nwọn nítorí àwọn ọlọ́jà yio ti fi owó kún ọjà nítorí èrò ti ó fẹ́ ra ọjà maa n pọ̀ si ni àsikò yi Pa pọ̀ mọ́ ipari ọdún ni àwọn ti ó fi ayẹyẹ ìyàwó, òkú, ọdún Kérésìmesì àti ṣíṣe miràn si àsikò yi Kò si ẹni ti kò ni nkankan Pé èniyàn ni ara li le tàbi ó lè jẹun, ó tó nkan Ilẹ̀ Yorùbá ni ohun ọrọ̀ ajé àti oúnjẹ ni oriṣiriṣi tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lati igbà ti Ìjọba àpapọ̀ ti da gbogbo ẹ̀yà orilẹ̀ èdè Nàíjíríà pọ̀ ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si pin owó epo rọ̀bì ni ìfẹ́ oúnjẹ àti ọjà òkèèrè ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di ọ̀lẹ àti ẹni ti kò ni ìrònú Oúnjẹ ilẹ̀ wa Àsikò tó lati ṣe àyípadà, ki a jẹ ohun ti a ba gbin ni ilẹ̀ wa, nítorí owó epo rọ̀bì ti gbogbo ilú gbójúlé ti fidi janlẹ̀ Ki owó epo rọ̀bì tó dé, a nfi ìrẹsì ṣe ọdún pàtàkì fún àwọn ọmọdé, ṣùgbọ́n iresi ti wọn gbin ni ilẹ̀ wa ni a njẹ Bi a ra oúnjẹ ilẹ̀ wa dipò oúnjẹ òkè-òkun, àgbẹ̀ yi o ri owó, a o si mọ irú oúnjẹ ti a njẹ ju ìrẹsì oníke ti wọn nkó wọ ilú Ki ṣe dandan ni ki a se ìrẹsì fún ọdún, a lè fi oúnjẹ ẹ̀yà miràn ṣe ọdún fún àwọn ọmọ Fún àpẹrẹ, Ìjẹ̀bú lè se ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ rirò àti iyán dipò ìkọ́kọrẹ́ fún ọdún tàbi ki Èkìtì se ìkọ́kọrẹ́ fún ọdún dipò iyán àti ẹ̀fọ́ rirò àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ Ẹ jẹ́ ki a gbé oúnjẹ ilẹ̀ wa lárugẹ Ìtàn fi yé wa wi pé Yorùbá ka ọ̀rọ̀ obinrin si ni àṣà Yorùbá bi ó ti ẹ jẹ wi pé obinrin ki jẹ Ọba nítorí ni àṣà ilú, ọkùnrin ló njẹ olóri Obinrin kò pọ̀ ni ipò agbára Àwọn ipò obinrin ni Ìyáálé, eyi jẹ́ ìyàwó àgbà tàbi ìyàwó àkọ́fẹ́ ninú ẹbí, pàtàkì ni ilé o ni ìyàwó púpọ̀ ṣùgbọ́n ọkùnrin ni olóri ẹbí Ipò obinrin kò pin si idi àdìrò àti inú ilé yókù gẹ́gẹ́ bi Olóri Òṣèlú Nàíjíríà, Muhammadu Buhari ti sọ Obinrin Yorùbá ti ni àyè lati ṣe iṣẹ́ ti pẹ́, bi ó ti ẹ̀ jẹ́ wi pé àwọn iṣẹ́ obinrin bi oúnjẹ ṣí ṣe, ẹní hí hun, aṣọ hí hun, aró ṣi ṣe, òwú gbi gbọ̀n, ọjà ti tà, oúnjẹ sí sè àti itọ́jú ẹbi ni obinrin nṣe Àwọn ọkùnrin nṣe iṣẹ́ agbára bi iṣẹ́ ọdẹ, alágbẹ̀dẹ, àgbẹ̀ tàbi iṣẹ́ oko iṣẹ́ fún ji jẹ àti mimu ẹbí Obinrin ni ògúná gbongbo ni oníṣòwò òkèèrè, eyi jẹ ki obinrin lè ni ọrọ̀ àti lati lè gba oyè Ìyálóde Fún àpẹrẹ, àwọn Ìyálóde ni ó njẹ Olóri ọjà ni gbogo ilẹ̀ Yorùbá àti alá-bójútó fún ọ̀rọ̀ obinrin Gẹ́gẹ́ bi àṣà ibilẹ̀ Yorùbá, àwọn ọkùnrin gbà ki ìyàwó wọn ṣe iṣẹ́ lati ran ẹbí lọ́wọ́, eyi lè jẹ́ nítorí àwọn ọkùnrin ni ìyàwó púpọ̀, nítorí èyi, kò nira bi ìyàwó kan tàbi méjì bá lọ ṣòwò ni òkèèrè, àwọn ìyàwó yókù yio bójú tó ilé Àṣà òkè-òkun fi fẹ́ ìyàwó kan àti ẹ̀sìn òkèère ti Yorùbá gbà ló sọ àdìrò di ipò fún obinrin àti Alá-bọ́dó, Ìyàwóilé tàbi Oníṣẹ́-ilé ti ó di iṣẹ́ obinrin Obinrin ayé òde òní kàwé, ṣùgbọ́n bi wọn kò ti ẹ kàwé, gbogbo ẹni ti ó bá ni làákàyè fún àṣà, kò gbọdọ̀ já obinrin si ipò kankan ni ilé nítorí obinrin ló ni gbogbo ilé ìròyìn tó gbòde ni ọ̀rọ̀ ìjọba-àpapọ̀ ti ó fẹ ki gbogbo ìpínlẹ̀ ni nàíjíríà pèsè àyè ni ọ̀fẹ́ fún àwọn darandaran lati tẹ̀dó dípò ki wọn ma kó mààlúù kiri ni ipinlẹ si ìpínlẹ̀ oníkálùkù lò ni iṣẹ́ tàbi òwò tirẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀ ló wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ yorùbá ni ayé àtijọ bi iṣẹ́ àgbẹ̀ ti ṣe pàtàki fún yorùbá bẹ ni ise darandaran jẹ́ fún fúlàní ni òkè-ọya ìyàtọ̀ ti ó wà ni àwọn iṣẹ́ mejeeji ni wi pé àgbẹ̀ ńṣe oko ni agbègbè rẹ nigbati darandaran ńda ẹran wọn kakiri lati ìlú kan si ekeji ilẹ̀ pọ̀ ju èrò lọ ni oke-ọya ju odò-ọya lọ ọ̀rọ̀ yorùbá ni a o ri ibi sùn ajá ńhanrun ìjà sèríà àti boko haram ti ṣi ọpọlọpọ ni idi kúrò ni òkè-ọya bọ́ si odò-ọya àyè kò tó fún ogúnlọ́gọ̀ ènìyàn ti ó ngbé ni odò-ọya pàtàki fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ó dari wále nítorí ija bókó haram àti ogun abẹ́lé yoku ni òkè-ọya yorùbá fẹran àlejò púpọ̀ darandaran ti nda ẹran wá si ilẹ̀ yorùbá lai si ìjà ọ̀na ti jin ọba ìjòyè àti ọlọ́rọ̀ àyè àtijọ́ ma nni agbo ẹran tàbi mààlúù ti àwọn fúlàní mba wọn tọ́jú ibùjẹ-ẹran tún wà ni il��̀-yorùbá ni àkùnnù-àkókó ni ayé òde òni kò bójú mu lati da ẹran kiri ni igboro àti ilú nlá di da ẹran kiri ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàmbá ọkọ̀ tó ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí lọ ki ẹran má a jẹ ohun ọ̀gbìn àgbẹ̀ àti ba oko jẹ kò bójú mu èyí ti ó́ burú ju ni darandaran ti ó ngbé ìbọn dání dípò ọ̀pá-ìdaran ti wọn ti pa olóko tori ki mààlúù lè jẹun ọ̀rọ̀ yorùbá ni a ò lè tori a ma jẹ́ran dọ̀bálẹ̀ fún mààlúù eleyi ló jẹ́ ki ẹgbẹ́ àgbẹ́kọ̀yà kọ ètò ìjọba àpapọ̀ lati pèsè ilẹ̀-ọ̀fẹ́ fún àwọn fulani ti ó nda ẹran ni ipinle yorùbá àti lati kọ ìyà lọ́wọ́ daran-daran ti o ngbé ìbọn lati da ẹran ni ilú òyìnbó àgbẹ àti àwọn ti o ńsin ẹran nri ìrànlọwọ gbà ni ọdọ ìjọba ó yẹ ki ijoba apapo pèsè irinṣẹ́ ìgbàlódé fún àwọn àgbẹ̀ àti ki àwọn ipinlẹ̀ pèsè àyè rẹpẹtẹ fún oko lati gbin oúnjẹ fún àwọn ogúnlọ́gọ̀ èrò ti ó pọ̀si odò-ọya ju ìpèsè ilé ọ̀fẹ́ fún darandaran ìmọ̀ràn fún ìjọba-àpapọ̀ ni ki wọn lo ilẹ̀ ti ó pọ̀ rẹpẹtẹ ni òkè-ọya pàtàki igbó sambisa ti àwọn bókó haram fi ṣe ibùjòkó tẹ́lẹ̀ ki ìjọba lọ́wọ́lọ́wọ́ tó lé wọn jade fun agbo mààlúù yorùbá ma npa ìtàn lati fi ṣe à ri kọ́gbọ́n tàbi fún ìkìlọ̀ ẹ ṣọ́ra lati fi ìbẹ̀rù àti ojo bẹ̀rẹ̀ ọdún nítorí a ma a géni kúrú lára ẹ̀kọ́ ti a lè ri fi kọ́ ọgbọ́n ni ìtàn ti a ka yi ni wi pé onikálukú ni ọlọrun fún ni ẹ̀bùn àti àyè ti rẹ̀ ni ayé ohun ti ó dára ni ìṣọ̀kan ẹ̀kọ́ wa lati kọ́ lára bi ẹranko ti ó ni agbára ṣe mba ara wọ́n gbé ó dára ki a gba ìkìlọ̀ àgbà tàbi ẹni ti ó bá ṣe nkan ṣáájú àti pé ìjayà tàbi ìbẹ̀rù lè gé ènìà kúrú bi o ti sọ ọmọ ẹkùn di ológbò ẹ ka ìtàn yi ni èdè gẹ̀ẹ́sì ni ojú ewé yorùbá lóri ayélujára ti a kọ ni ọdún ẹgbàálémẹ́rìndínlógún oṣù kẹta ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n ọlọrun ki ó dáwọ́ àbíkú àgbà dúró ki ó si tu bàbá olóògbé gómìnà èkó tẹ́lẹ̀ aṣíwájú bọ́lá ahmed ìyàwó àwọn ọmọ àti gbogbo ẹbí ninú ki èdùmàrè dá ikú ọ̀dọ́ dúró kó tu gbogbo àwọn ti irú ọ̀fọ̀ bẹ́ ẹ̀ bá ṣẹ̀ ninú òwe yorùbá sọ wi pé bi iná bá kú á fi eérú bojú bi ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá kú á fi ọmọ ẹ rọ́pò òwe yi fi hàn ipò ti yorùbá fi ọmọ si kò si ẹni ti kò ni kú ṣùgbọ́n ọ̀fọ̀ nlá ni ikú ọmọ jẹ́ fún òbí àti àwọn ti olóògbé bá fi silẹ̀ pàtàki àbíkú àgbà ìròyìn ikú jidé tinubu àrólé gómìnà èkó tẹ́lẹ̀ aṣíwájú bọ́lá ahmed tinubu kàn pé ó jade láyé ni ọjọ́rú ọjọ́ kini oṣù kọkànlá ọdún ẹgbàálémẹ́tàdínlógún oriṣiriṣi wèrè ló wà nítorí pé ki ṣe wèrè ti ó wọ àkísà ni ìgboro tàbi já sita nikan ni wèrè ẹnikẹni ti o nhu ìwà burúkú tàbi ṣe ìpinnu burúkú ni yorùbá npè ni wèrè ìpinnu ṣi ṣe ṣe pàtàki ni ayé àtijọ́ àti òde òní òwe yorùbá sọ wi pé bi ará ilé ẹni bá njẹ kòkòrò búburú hẹ̀rẹ̀-huru rẹ̀ kò ni jẹ́ ki a sùn ni òru àbáyọrí ìpinnu tàbi èrò burúkú kò pin si ọ̀dọ̀ ẹbi àwọn ti ó wà ni àyíká elérò burúkú ó lè kan gbogbo àgbáyé fún àpẹrẹ kò si ìyàtọ̀ laarin wèrè tó já sita nítorí wèrè ni yorùbá npe ọkọ tàbi ìyàwó ti ó ni ìwà burúkú ẹbi burúkú ọba ti ó nlo ipò rẹ lati rẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àti òṣèlu ti ó nja ilú ni olè lati kó owó ti wọn ji lọ si òkè òkun nibiti ohun amáyédẹrùn ti ilú wọn kò ni wà gẹ́gẹ́ bi òwe yorùbá ti ó sọ wi pé a ki sọ pé ki wèrè ṣe òkú ìyá rẹ̀ bi ó bá ṣe ri bi ó bá ni òhun fẹ́ sún jẹ nkọ́ ìtumọ̀ òwe yi ni wi pé ìpinnu pàtàki bi ìyè àti ikú kò ṣe é gbé lé wèrè lọ́wọ́ ó yẹ ki àwọn ènìyàn gidi ti ori rẹ pé dásí ọkọ tàbi ìyàwó ọba tàbi àwọn ti ó wà ni ipò agbára òṣèlu ti o nfi ipò wọn jalè àti àwọn ti ó nhu ìwà burúkú yi lati din àbáyọrí ìwà burúkú lóri ẹbí alá-dúgbò àti àgbáyé kù ogún jẹ́ gbogbo ohun ìní ti bàbá tàbi ìyá bá fi silẹ́ ti wọn bá kú ni ìgbà àtijọ́ kò wọ́pọ̀ ki olóògbé ṣe ìwé-ìhágún bi wọn ṣe má a pín ohun ini wọn lẹhin ikú ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ki i ni ọrọ̀ bi ti àwọn ọkùnrin nítorí wọn ki i ni ogún bi ilé ilẹ̀ tàbi oko bi wọn ba ti fẹ ọkọ pàtàki bi ẹbi bá ti gba nkan orí ìyàwó wọn kò tún lè padà wá gba ilé ilẹ̀ tàbi oko ni ilé bàbá wọn nítorí eyi ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin kò ni ohun ini púpọ̀ ọkùnrin ló ni oko ilé àti ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àṣà àdáyé ba nítorí àwọn ni àrólé ti ó njẹ́ orúkọ ìdílé àwọn obìnrin yorùbá bi ìyá tinubu ẹfúnṣetán iyalode ìbàdàn ìyá tẹ́júoṣó mọ nipa iṣẹ́ òwò púpọ̀ àti pé láyé òde òni àwọn obìnrin ti bẹ̀rẹ̀ si kàwé lati lè ṣe iṣẹ ti àwọn ọkùnrin nṣe tẹ́lẹ̀ nítorí eyi lati ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin àwọn obìnrin yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ si ni ohun ini bi ilé ilẹ̀ owó tàbi oko ti ọmọ lè jogún lẹhin ikú bàbá tàbi ìyá lai si ìwé-ìhágún àwọn ẹbí ni àṣà àdáyébá ti wọn fi le pín ogún fún àwọn ọmọ olóògbé àwọn ẹbí miran lè lo orí ò jorí tàbi idi-igi ti ó bá jẹ ogún bàbá ọ̀rọ̀ yorùbá ni bàbá gbogbo ayé nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ bàbá lo ni ìyàwó púpọ̀ ìdí ti ogún bàbá ṣe lè mú ìnira wá ni wi pé ohun ti wọn bá pín fún idi-igi kan lè fa owú jijẹ fún idi-igi miran eyi si ma a ndá ìjà silẹ̀ lẹhin ikú bàbá eyi pẹ̀lú idi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ki i náání ohun ini bàbá lẹhin ikú irú bàbá bẹ́ ẹ̀ ìgbà miran idi-igi ti o jogún ilé lè má lè tọ́jú rẹ titi yio fi wó àwọn ilé ti wọn kò tọ́jú ogún ìyá ko ti bẹ̀rẹ̀ si fa ìjà bi ti bàbá ó lè jẹ́ wi pé nítorí àwọn obìnrin ti o ni ogún ti wọn lè jà lé kò ti pọ̀ tó bi ti àwọn ọkùnrin ti o ni ìyàwó àti ohun ìní rẹpẹtẹ yorùbá ni ọmọ ti a kò kọ́ ló ngbé ilé ti a bá kọ́ tà ọmọ ti ó bá njà du ogún ma nba ogún jẹ ni lati din rògbòdiyàn ti ogún ma nfà ó yẹ ki bàbá tàbi ìyá ṣe ìwé-ìhágún ki wọn fún ọmọ ni ẹ̀kọ́ ilé àti ẹ̀kọ́ ilé-iwé ti ọmọ kò ni fi jà du ogún bàbá tàbi ti ìyá lẹhin ọdún kọkàndinlógún ikú olóògbé olóyè m.k.o abíọ́lá aàrẹ ọ̀na kakanfo yorùbá kẹ̀rinlá ọba lamidi adéyẹmi yan ọ̀túnba gani adams si ipò aàrẹ ọ̀na kakanfo yorùbá karùndinlógún ọ̀túnba gani adams ni olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ọmọ oòduà ti wọn dá silẹ̀ ni ọjọ́ karùndinlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún kẹtàlélógún sẹhin ni mushin kò bojú wẹ̀hin lati ọdún kẹtàlélógún lati má a jà fún yorùbá lati gba ẹ̀tọ́ iyì àti gbi gbé àṣà yorùbá ga kakiri àgbáyé fún akitiyan yi wọn ti fi jẹ oyè méjìlélaadọta kakiri ṣùgbọ́n adé gbogbo oyè yi ni aare ona kakanfo bi àwọn alatako diẹ ti wa ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbàgbà yorùbá ti fi ọwọ́ si yin yan ọ̀túnba gani adams si ipò aare ona kakanfo karùndinlógún lára àwọn enia pàtàki ti ó ki kú ori ire ni ọọni ifẹ̀ gómìnà bọ́la tinubu gómìnà rauf arẹ́gbẹ́sọlá àwọn ọ̀gá olórin àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ olùkọ̀wé yorùbá lóri ayélujára kí ọ̀túnba gani adams kú ori ire oyè á mọ́rí o ẹ ò ni kú léwe ẹmi ọlá á gùn lati má a jà fún yorùbá àti lati gbé àṣà yorùbá lárugẹ si ni gbogbo àgbáyé àwọn iwé ìròyìn gbe jade wi pé adébáyọ̀ fálétí ògúná gbòngbò ninú àwọn ti ó gbé èdè àti àṣà yorùbá lárugẹ ni àgbáyé re ibi àgbà nrè ni ọjọ́ ìsimi ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù keje ọdún ẹgbàálémẹ́tàdinlógún ọmọ ọdún mẹrindinlaadọrun ni olóògbé fálétí ki wọn tó jade láyé olóògbé adébáyọ̀ fálétí relé ni ìgbá ayé olóògbé adébáyọ̀ fálétí ó jẹ́ ìkan ninú àwọn òṣìṣẹ́ àkọ́kọ́ ni ilé iṣẹ́ amóhùn-máwòrán àkọ́kọ́ ni ilẹ̀ aláwọ̀dúdú ti wọn dá sílẹ̀ ni ìbàdàn ti ó jẹ́ olú ilú ẹ̀yà yorùbá ni ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀ èdè nàíjíríà ó gbé èdè yorùbá lárugẹ nipa ṣi ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì si èdè yorùbá ó kọ ìwé itumọ̀ ọ̀rọ̀ nipa li lo orúkọ yorùbá kò tán síbẹ oníròyìn ni ó fi eré ìtàgé gbé èdè yorùbá lárugẹ nipa di dá ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ọ̀yọ́ fún ìgbéga eré ìtàgé silẹ̀ ni ọdún méjìdinlaadọrin sẹhin lára àwọn eré yorùbá ti olóògbé adébáyọ̀ fálétí kọ ti ó si ṣe ni mágùn àfọ̀njá baṣọ̀run gáà àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ́ lọ ẹ̀kọ́ pọ̀ fún ọ̀dọ́ ayé òde òní lati kọ́ lára ìgbésí ayé olóògbé adébáyọ̀ fálétí lára ẹ̀kọ́ yi ni wi pe ìwé kí kà ṣe pàtàkì bi kò ti ẹ̀ si ìrànlọ́wọ́ lati ka ìwé ni ọmọdé bi enia bá ka ìwé ni àgbà yio wúlò olóògbé adébáyọ̀ fálétí padà si ilé-ìwé lati lọ pari ìwé mẹfa ti ó dá dúró nigbati kó si agbára fún bàbá rẹ lẹhin eyi ó fi àgbà ara ka ìwé ni ilé-ìwé ẹ̀kọ́ giga ó gbé ìgbésí ayé rere nipa ìtọ́jú àwọn ọmọ àti ìyàwó ó si fún àwọn ọmọ ni ẹ̀kọ́ ilé àti ti ilé-ìwé fún àwon iṣẹ́ ribiribi yi olóògbé adébáyọ̀ fálétí gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn àpínfún ni orilẹ̀ èdè nàíjíríà àti ni òkè-òkun ìjọba-àpapọ̀ sọ èkó di ìpínlẹ̀ ni àádọ́ta ọdún sẹhin èkó jẹ́ olú ilú fún gbogbo orilẹ̀ èdè nàíjíríà tẹ́lẹ̀ ki wọn tó gbe lọ si abuja ìpínlẹ̀ èkó jẹ ikan ninú ipinle mẹ́fà yorùbá yorùbá ni èkó gba olè ó gba ọ̀lẹ ọ̀rọ̀ yi jẹ wi pé kò si irú ẹni ti ko si ni ìpínlẹ̀ èkó nítorí èkó gba olówó ó si gba aláini àti wi pé iṣẹ́ pọ̀ ni èkó ju gbogbo ìpínlẹ̀ yoku lo kò si ẹ̀yà tàbi ẹ̀sìn nàíjíríà ti kò si ni èkó nítorí èyi èrò pọ̀ jù ilẹ̀ lọ nítorí omi ló yi èkó ká ìnáwó rẹpẹtẹ ni ìsìnkú arúgbó jẹ́ ni ilé yorùbá bi arúgbó bá kú ni ilé yorùbá ki ṣe òkú ọ̀fọ̀ ṣùgbọ́n òkú ijọ àti ji jẹ mi mu ni pàtàki bi irú arúgbó bá bi àwọn ọmọ ti ó ti dàgbà gbogbo ẹbi ará àti ilú yi ó parapọ̀ lati ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin fún irú arúgbó bẹ́ ẹ̀ àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ yi o ṣe oriṣiriṣi ẹ̀yẹ ìbílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ lati gbé ìyá tàbi àgbà bàbá àgbà relé bi eléré ìbílẹ̀ kan ti nlọ ni òmíràn yio de eleyi lo njẹ́ ki ilú kékeré dùn Ẹ jẹ́ k'á sọ Yorùbá Mo tàka òṣì dànùn Ọ́lọ́run má jẹ́ kò ṣẹlẹ̀ Ọ́lọ́run má jẹ́ A kì í ríwà oníwà ká fọwọ́ jurí Mo gbà tọkàntọkàn, mo gbà taratara Jẹ́ èbúrẹ́, awo olùgbẹ́bẹ̀ Ẹ jọ̀wọ́, má bínú Mo yíká ọ̀tún, mo yíká òsì, ki adé pẹ́ l'órí, ki bàtà pẹ́ l'ẹ́sẹ̀, ki ìrùkẹ̀rẹ̀ pẹ́ l'ọ́wọ́, ki àṣe pẹ́ l'ẹ́nu, kábíyèsí, aláṣẹ èkejì òrìṣà Ọjọ́ ìkúnlẹ̀ bí ìgbà tí Orò n lọ̀run ni lára gbogbo abiyamọ àti ibi àti ire, wọn jọ̀ nrìn ó bajẹ́ bí ọwọ́ òsì ọwọ́ ọ̀tún ọwọ́ òsì Olòṣì ọmọ ní ńfọwọ́ òsì júwe ilé baba ẹ̀ Ṣe kíá kí o má bá fi ìka àbámọ kan ẹnu Ilẹ̀ mo pe o! Dá mi l'óhún Bí ọmọdé bá l'áṣo bí àgbà kò lè ní àkísà bí àgbà Mo n sọ òtítọ́ fún ẹ Òtítọ́ ní mo n sọ fún ẹ Òtítọ́ dọ́jà ó kùtà, owó lọ́wọ́ là ńra èké Ẹ jọ̀ọ́, ṣí fèrèsé Kíni itúmọ̀ fèrèsé Bíbíre kò ṣeé fi owó rà Ìrèké ò ní ibùdó; ibi gbogbo ló gba alágbára Ìwà rere lẹ̀ṣọ́ ènìyàn Bó pẹ́ bó yá, agogo tó lu méjìlá, ńbọ̀ wá lù kan A kì í pẹ̀lú ọ̀bọ já'ko Tí afọ́jú bá ní òun yóò fọ́'ni lójú, ó yẹ ká funra; tí kò bá mú nǹkan lọ́wọ́, ó lè tẹ nǹkan mọ́'lẹ̀ Ó di ìgbà tí òjò bá dá kí alágborùn tó mọ̀ pé ẹrù lòún gbé Kí a dé igbó kí a má fọ'hùn ló ńmú ẹyẹ oko ṣu síni lórí Ẹyìn tí yóò di epo, yóò tọ́ iná wò Tí àdúrà bá gbà tán, apá aládúrà ò ní ka Agbọ́n tí géńdé rí tó ńsá, ni aláàmù ńṣà jẹ lẹ́ẹ̀gbẹ̀ ògiri Ọgbọn ọgbọ́n, ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀, làgbàlagbà fi ńsá fún màlúù Ẹni ejò bá ti bùjẹ rí, bó bá rí ekòló, yóò họ Àìtètè mú olè, olè á mú olóko Kàǹga tó jìn kì í pariwo A kò lè tìtorí pé ọ̀nà jìn kí a wà padà sẹ́hìn A kì í mọ orúkọ Ọlọ́run, kí ìyà ó jẹ'ni Obì tó bá fara pamọ́, ló máa ńgbó Odò tó ńṣàn, kì í b'ojú w'ẹ̀hìn Bí inú bá bí baba tó bá gbé ọmọ rẹ̀ jù sí inú èèrùn, bí inú rẹ̀ bá rọ̀, inú èèrùn lè má rọ̀ Àdáníkànrìn ejò ló ńjẹ ọmọ ejò níyà Gbogbo ohun tó ńdán kọ́ ni wúrà Ayé tí ẹṣin ò jẹ, tí ìrù ìdí ẹ̀ bá ní sùúrù, aá jẹ jù bẹ́ẹ̀ lọ Omi tí èyàn máa mu, kò ní ṣàn kọjá rẹ̀ Kó dùn, kó pọ̀, kó pẹ́, Ọlọ́run ló ńfún ni Kí àgbàdo tó dé áyé, adìyẹ ńjẹun Bí agbọ́n ṣe lóró tó, oúnjẹ ni fún aláǹgbá Gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan a máa yí ìpinnu ogún ọdún padà Bí a kò bá tí ì jókòó, a kì í na ẹsẹ̀ Ẹranko tó bá ṣiyèméjì lọdẹ ńpa Ojú ẹní máa là, á rí ìyọnu Adániwáyè ò gbàgbé ẹnìkan; àìmàsìkò ló ńdààmú ẹ̀dá Omi tó tán lẹ́hìn ẹja ló sọọ́ di èrò ìṣasùn Kò ní burú fún ọlọ́de títí, kó rí ológbò kó lọ yọ ìbọn Ìbínú kìí pẹ́ sọ ilé olówó rẹ̀ dahoro Sùúrù ni baba ìwà; àgbà tó ní sùúrù, ohun gbogbo ló ní Àtùpà kì í níyì lọ́ọ̀sán, ṣugbọ̀n a máa gbayì lọ́jọ́ alẹ́ Tí agbada ò bá gbóná, àgbàdo ò lè ta Ojú tó rí ibi tí ò fọ́, ire ló ńdúró de Tí a bá wo dídùn ifọ̀n, àá họ ara dé egun Kòkòrò tó ńjó lẹ́ẹ̀bá ọ̀nà, onílù rẹ̀ ńbẹ nínú igbó Kí a tó dé ibi tí à ńlọ, a máa ńkọ́kọ́ dé ibi tí a kò fẹ́ Tí aṣeni bá ní ibi mẹ́fà, yóò fi ìkan tàbí méjì ṣe ara rẹ̀ Ojú ló ńkán owó tó sọnù; ìgbà wo ni níná ò ní kàn án tẹ́lẹ̀ Ẹni tí òjò ò pa, tí òrùn ò pa, ebi ni yóò paá Ẹni a ṣe lóore tí ò dúpẹ́, bí ìgbà tí ọlọ́ṣa ko ni lẹ́rù lọ ni Ọ̀nà ò ní jìn kó má lóòpin Àlùya ni ìlù ọ̀fẹ́ Ó di ẹ̀hìn ìgbín kí a tó fi ìkarahun rẹ̀ họ ìkòkò Ọwọ́ kì í pẹ́ ní isà àkeekè Ká fi ogún ọdún lá oyin kò ní kí inú ẹni dùn Opó tó ńronú ọkọ rẹ̀ tó kú, yẹ kó tún máa rántí ọkọ rẹ̀ tó kù Èyí ó wù á wí, t'Olúwa làṣẹ Gbogbo èèyàn oníwà tútù kọ́ lonínúure Yàrá kékeré gba ogún ọ̀rẹ́ Eṣinṣin tí kò bá gbọ́ ikilọ ló ńbá ọ̀gẹ̀dẹ̀ wọ ẹnu ọ̀bọ Ewúrẹ́ tó lè kígbe jù, kọ́ lebi ńpa jù Ẹyẹ tó bà lórí igi tí ò ké, ẹ̀yìn ọ̀rọ̀ ló ńrò Àgbẹ̀ tí kòkó ẹ̀ẹ́ yè, layé ló mọ̀ọ́ ṣe Iná l'ọmọ aráyé lè pa kò s'ẹ́ni tó lè pa èéfín Nínú òròmọ adìyẹ àti ẹyin rẹ̀, ọ̀kan lèyàn máa fọwọ́ mú A kì í mọ iyì wúrà tí kò bá sọnù Agbọ́n sẹ́, oyin sẹ́, ojú olóko rèé, gòdògbò godogbo Èébú álọ ni ti ahun, àbọ̀ ti àna rẹ̀ ni Ayé ò ní le títí kí a fi inú omi ṣe ibùgbé Ẹni tí kò bá lè jìyà tó kún ahá, ò lè gbádùn ọrọ̀ tó kúnnú àmù Kò sí ohun tó pọ̀ tí kì í tán, àfi ọlá Ọlọ́run Ọ̀pọ̀lọ́ gbé ọmọ sílẹ̀ ó gbé ọkọ pọ̀n, ó lọ̀rọ̀ ọkọ bàǹtà banta ni Ẹni ejò bá ti bùjẹ rí, bó bá rí ekòló, yóò họ Àgbẹ̀ tó ro oko tí kò gbin ọkà lóun dá ikún lóró ikún kọ́ ló dá lóró, ara ẹ̀ ló dá lóró Mo gbọ́n tán, mo mọ̀ọ́ tán, lagbọ́n ò ṣe lóró bí oyin \ No newline at end of file