diff --git "a/yorubaCorpus/YcorpussssxL_0.txt" "b/yorubaCorpus/YcorpussssxL_0.txt" new file mode 100644--- /dev/null +++ "b/yorubaCorpus/YcorpussssxL_0.txt" @@ -0,0 +1 @@ +Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́. èdè Yorùbá. Sísọ ní. Lílò bíi oníbiṣẹ́ kò sí ojúewé yìí Àkóso lọ́wọ́ Kòsí àkóso oníbiṣẹ́ Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè Èdè Yorùbá. Ní báyìí, tí a bá wo èdè Yorùbá, àwọn onímọ̀ pín èdè náà sábẹ́ ẹ̀yà Kwa nínú ẹbí èdè Niger-Congo. Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀yà Kwa yìí ló wọ́pọ̀ jùlọ ní sísọ, ní ìwọ̀ oòrùn aláwọ̀ dúdú fún ẹgbẹ̣ẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn onímọ̀ èdè kan tilẹ̀ ti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé láti orírun kan náà ni àwọn èdè bí Yorùbá, Kru, Banle, Twi, Ga, Ewe, Fon, Edo, Nupe, Igbo, Idoma, Efik àti Ijaw ti bẹ̀rẹ̀ sí yapa gẹ́gẹ́ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó dúró láti bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀dún sẹ́yìn. Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èdè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni èdè Yorùbá. Àwọn ìpínlẹ̀ tí a ti lè rí àwọn tó n sọ èdè Yorùbá nílẹ̀ Nàìjíríà norílẹ̀ èdè Bìní. Tógò àti apá kan ní Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà bí i Cuba, Brasil, Haiti, àti Trinidad. Ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ, yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òwò ẹrú ni ó gbé àwọn ẹ̀yà Yorùbá dé ibè Èdè Yorùbá jẹ́ èdè kan ti ó gbalẹ̀ tí ó sì buyì kákàkiri àgbáyé. Ìtàn sọ fún wa pé ní àgbáyé Kwa ní èdè Yorùbá bátan; kwa jẹ́ iyè kan ní Niger Congo. A lèè sọ pé àwọn tí wọ́n ń sọ èdè Yorùbá yàtọ̀ sí orílẹ̀ èdè Nigeria lé ní Ọgbọ̀n nílíọ̀nùn, àwọn orílẹ̀ èdè tí a ti ń sọ èdè Yorùbá yàtọ̀ sí Nigeria ni. Togo, Ghana, Serria leone, Brazil, United Kingdom àti United State. Èdè Yorùbá pín sí orísirísi ẹ̀ka ní àkọ́tán, ó sì ti di gbajúgbájà ni orílẹ̀ èdè Nìgeria àti àgbáláayé lá papọ̀. Àwọn nnkan tí ó ń gbé èdè Yorùbá níyì. Òwe:- Orísirísi ọ̀nà ni a le gbà pa òwe. A le pa òwe gẹ́gẹ́ bí àwọn elédè ti ń pa á tàbí bí gbogbo ènìyàn ti ń pá gan-an. Bí àpẹẹrẹ: Àíyá bẹ́ sílẹ̀ ó bé áré, igi ọ̀ún ni kò ga. A le pa owe da, bí àpẹẹrẹ: Ojú kì í ti eégún kí ọmọ alágbàá má kọrí sóko. Ojú kì í ti eégún nínú aṣọ Ohun ti i tan leegun ọdun, ọmọ alagbaa a kọri sokò. Akànlò èdè Lílò àmìn ohùn ÌLÒ ÈDÈ YORÙBÁ Àwọn èròngbà kòòsí ìlò èdè Yorùbá yíì ni pé mo fẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ èdè Yorùbá lo dáradára nítorí náà a wo ìjúba ni awùjọ Yorùbá, a wo ààtò, Ìtúmọ̀, ìlò, àti àgbéyẹ̀wò àwọn òwe, àkànlò èdè àti ọ̀rọ̀ àmúlò mííràn. A wo èdè àmúlò nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ àti igba ti a ba kọ èdè Yorùbá silẹ. A wo ẹ̀bùn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀. A sí wo ìlànà ati òté tó de sísọ̀rọ̀ ni àwùjọ Yorùbá. A wo ìwúrẹ láwùjọ Yorùbá. A wo aáyan àròkọ kikọ. Lábẹ́ àròkọ, a wo arokọ wọ̀nyí: alapejuwe, ajemọroyin, alalaye, alariiyan, onisiipaya, ajẹmọ́-ìsonísókí-ìwé ati arokọ onileta. A wo bi a ṣe n se agbekale isẹ to da le girama, iwe atumọ, ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ, àbọ̀ ìpàdé, ìjábọ̀ ìwádìí, ìwé ìkéde pélébé àti eyí ti a fi n se ìpolongo ti a máa ń tẹ̀ mọ́ ara ògiri. Èdè Yorùbá ni ibamu pẹlu asa obínibí Yorùbá. Ó yẹ kí a mọ ọ̀rọ̀ í dá sí. Ó yẹ ki a mọ ọ̀rọ̀ sọ, ki á si mọ ọ̀rọ̀ ọ́ kọ sílẹ̀ lẹ́yìn ìgbà ti a bá ka ìwé kékeré yìí. BÍ ÈDÈ YORÙBNÁ SE DI KÍKỌ SÍLẸ̀ Kí àwọn òyìnbó tó dé, kò sí ètò kíkọ ati kíka èdè Yorùbá. Gbogbo ọ̀rọ̀ àbáláyé tí ó ti di àkosílẹ̀ nísinsìnyí nínú ọpọlọ́ àwọn baba ńlá wa ni wọ́n wà tẹ́lẹ̀. Irú àwọn ọ̀rọ̀ àbáláyé báyìí a máa súyọ nínú orin, ewì àti ìtàn àwọn baba wa. Nígbà tí a kọ́ ń pe gbogbo àwọn ẹ̀yà tí èdè wọ́n papọ̀ yìí ní Yorùbá tàbí Yóòbá, wọn kò fi tara tara fẹ́ èyí nítorí pé àwọn ẹ̀yà Yorùbá ìyókù gbà pé àwọn Ọ̀yọ́ nìkan ni Yorùbá. Nígbà tí àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run aláwọ̀ funfun tó wá wàásù nípa kírísítì ṣe àkiyèṣí pé èdè wọ́n bá ara wọn mu ni wọ́n bá pè wọ́n ní Yorúbà tàbí Yóòba. Àwọn Yorùbá ti a ko l’éní lo si ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí a sì wá dá padà sí sàró lẹ́hìn tí òwò ẹrú tí tán ni àwọn òyìnbó Ìjọ C.M.S. kọ́kọ́ sọ di onígbàgbọ́. ABUDA ÈDÈ YORÙBÁ Àbùdá èdè Yorùbá ni ó máa jẹ́ kí á mọ ohun tí èdè jẹ́ gan-an. Orísirísi ni àwọn àbùdá tí èdè Yorùbá ní. Èdè Yorùbá kógo àbùdá wọ̀nyí já. Ohun tí a bá pè ní èdè gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí a fí ìró èdè gbé jáde. Ìró yìí ni a le pè ní ariwo tí a fi ẹnu pa. A ó ṣe àkíyèsí pé èyí yàtọ̀ sí pípòòyì, ijó ọlọ́bọ̀ùnbọ̀un, dídún tàbí fífò tata tàbí jíjuwó alákàn sí ara wọn. Èdè nílò kíkọ́ ọ fún ìgbà pípẹ́ díẹ̀ kí ènìyàn tó le sọ ọ́. Ó ti di bárakú tàbí àṣà fún wa pé a gbọ́dọ̀ kọ́ ọmọ tí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ni èdè. Àkiyèsí àti ìwádìí yìí ni àwọn eléde gẹ̀ẹ́sì ń gọ́ka sí nígbà tí àwọ́n ba sọ pé. Ọmọ tí a bá ṣẹ̀ṣè bí tí a kò kọ́ ní èdè, àti àwùjọ jẹ́ kòríkòsùn. Ìhun ni èdè ènìyàn gùn lé tàbí dálé. Bí a ṣe hun ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú gbólóhùn ṣe pàtàkì kíkà iye ìró èdè nínú gbólóhùn kò fi ibi kankan ní ìtúmọ̀. A lè sọ pé ìyàndá ṣubú ìyàndá ẹlẹ́mu ṣubú Ó ṣubú Ìyàndá tí a ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣubú. Ìyípadà orírsirísi ló le wáyé sí gbólóhùn wọ̀nyí tí yóò sì da ètò wọn ní, síbẹ̀síbẹ̀, yóò ní ìtumọ̀. Irú àbùdá yìí ni onímọ̀ ẹ̀dá-èdè ń pè ní “Structure dependence”. Gbogbo èdè kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ìró èdè tirẹ̀ tí a ń pè ní Fóníìmù. Foniimu yìí sún mọ́ ti àwọn ẹranko ṣùgbọ́n ó sì tún rọ̀ jut i ẹranko lọ. Ó yàtọ̀ láti èdè kan sì òmíràn. Bí a bá mú fóníìmù yìí lọ́kọ̀ọ̀kan. kì í dá ìtumọ̀ ní kó wúlò ìgbà tí a bá kàn án pọ̀ mọ́ fóníìmù mìíràn gan-an ló máa ṣìṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ ìró èdè /a/ /b/ /d/ /e/ /ẹ/ kò dá ìtumọ̀ ní, àfi tí abá kàn wọ́n papọ̀ lọ́nà orísirísi. A lè se àkànpọ̀ kí á ri ọ̀rọ̀ bí  abẹ, baba, adé, alẹ́ abbl. Irúfẹ́ àkiyèsí àti ìwádìí yí ni àwọn onímọ̀ ẹ̀dà-èdè ń pe gẹ̀ẹ́sì rè ní “duality” tàbí “double articulation” ìwádìí fihàn pé àwọn ẹyẹ àti ẹranko tí wọ́n ní ìró èdè kò pò, iye èdè tí òkọ̀ọ̀kan ní kò pọ̀ pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ adìyẹ ní ìró èdè bí ogún, ti mààlúù jẹ́ mẹ́wàá ṣùgbọ́n kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ọgbọ̀n Èdè jẹ́ ohun ètò tí a máa ń lò láti ṣe àròyinlẹ̀. ÌWÚLÒ ÈDÈ YORÙBÁ Èdè wúlò fún kí a le bá ara sọ ọ̀rọ̀ léyìí tí ó máa ń fa àgbọ́yé àti àjọṣepọ̀ A máa ń lo èdè láti fi pèṣẹ̀ Èdè la fi ń kọ tàbí sọ ìtàn orísìrísi, ìbáà jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà. A máa ń fi èdè fa ẹwà yọ nínú afọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ akéwì ni ó máà ń lo èdè Yorùbá ti a ó sì gbédìí fún ẹwà akéwì náà. A kò le ṣe kí a má kí ara wa ní orísirísi ọ̀nà bóyá ọ̀rẹ́ sí ọ̀rẹ́, pẹ̀lú orísirísi ẹwà èdè. Èdè wúlò fún fífi sọ èrò ọkàn wa àti fífi ìtara hàn sí ohun tí a gbọ́ rí tàbí tí ó ṣelẹ̀ sí wa. Èdè Yorùbá àti ìmọ̀ ẹ̀dà èdè Àgbéyẹ̀wò ìlò èdè Yorùbá Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ Ètò ìtọ́sọ́nà Àwọn irinṣẹ́ àdáni Ẹ kò tí w'ọlé Ọ̀rọ̀ nípa àtúnṣe láti àdírẹ́ẹ̀sì IP yìí. Ọ̀rọ̀ fún IP yí Ó dára kí ẹ dá àkópamọ́ kí ẹ sì ṣe ìtẹ̀jáwọlé, ṣùgbọ́n kò pọn dandan A gbà yín níyànjú kí ẹwọlé, bótilẹ̀jẹ́pẹ́ kò pọndandan. Àwọn orúkọàyè Ìfihàn inú ojúewé Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ nípa ohun inú ojúewé yìí Àwọn oriṣiríṣi Se àtúnṣe ojúewé yi Àwọn àtúnṣe tókọjá sí ojúewé yìí Wo ìtàn Lọ sí ojúewé tó ní orúkọ yìí tí ọ́ bá wà Àbẹ̀wò sí ojúewé àkọ́kọ́ Ojúewé Àkọ́kọ́ Ìpele Àyọkà Ìròhìn lọ́wọ́lọ́wọ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ Ẹ ṣe àrìnàkò ojúewé kan Ojúewé àrìnàkò Àkójọ àwọn àtúnṣe tuntun nínú wiki. Fún ìrànlọ́wọ́. Tíwálẹ́yìn Se ẹ̀bùn owó Àkójọ gbogbo ojúewé wiki tó jápọ̀ s'íbí Ìjápọ̀ mọ́ ojúewé yí Àwọn àtúnṣe tuntun nínú àwọn ojúewé tójápọ̀ láti inú ojúewé yìí Àtúnṣe tó báramu Àwọn ojúewé pàtàkì Àjápọ̀ sí dátà àjápọ̀mọ́ra ẹyọ ìnú ìkọ́pamọ́ Ẹyọ inú Ìdáhùn-ìbéèrè lórí bí a ṣe le tọ́ka ojúewé yìí Ẹ ṣe ìtọ́ka ojúewé yìí Ojúewé tí ó ṣe é tẹ̀ ṣ'íwèé Àtẹ̀jáde tóṣeétẹ̀síìwé Àwọn èdè míràn Àtúnṣe àwọn àjápọ̀ èdè míràn" Àtunṣe ojúewé yi gbẹ̀yìn wáyé ni ọjọ́ 18 Oṣù Kẹ̀sán 2016, ni ago 08:08. Gbogbo ìkọ wà lábẹ́ ó ṣe é ṣe kí àwọn ọ̀rọ̀ àdéhùn míràn tún wà. Ẹ wo Àwọn Ọ̀rọ̀ Àdéhùn Ìlò fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. ni àmììtajà fífilórúkọsílẹ̀ Ètò àbò Ìkìlọ̀ gbogbo Àwọn olùgbédàgbà Ẹkú dédé àsìkò yìí ẹ̀yin ọmọ ogun. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́kí á tún bọ̀ sọwọ́pọ̀ láti gbé ògo ilẹ̀ Yorùbá ga. Inù mi dùn púpọ̀ sí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀ẹ̀tí kẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Yorùbá yálà nílẹ̀ Yorùbá tàbí ní òkè òkun bá lè bẹ̀rẹ̀ láti máa kọ́ ọ̀pọlọ̀pọ̀ nínú àwọn àròkọ wọn ní èdè abínibí wà nítorí òní kọ́ àmọ́ nítorí ọjọ́ ọ̀la kí àwọn ọmọ tí wọn kò ì tíì bí lè rí nnkan kà nípa gbogbo ohun mère mère tí ó n sẹlẹ̀ jákè jádò àgbáyé. Tí a bá wo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sì ní máa gbérí níwọ̀n ọgbọ́n ọdún sẹ́yìn a ri wí pé púpọ̀ nínú wọn ni wọn fi èdè abínibí kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ́n, kòsí iṣẹ́ìwádìí kan tí wọ́n se tí wọ́n kò kọ ní èdè wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé èdè gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n gbà fi se ìwádìí náà. Ó seni láànu láti máa pàdé àwọn ara ilé nílu òyìnbó kí wọ́n máa fara pamọ́ ki a máà ba pè wọ́n ní ọmọ Yorùbá. Ogún lọ́gọ̀ àwọn olùkọ́ni nílu òyìnbó ni wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Yorùbá sùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo akitiyan wọn kò sí ọ̀kan soso nínú isẹ́ ìwádìí wọ́n pẹ̀lú aroko tí ó wà ní èdè Yorùbá Kí ló dé Ọ̀rọ́ tán lẹ́nu sùgbọ́n ó pọ̀ níkùn Títí di ọjọ́ mìíràn ọjọ́ ire, Emi ni tiyín ní tòótọ́, Ọmọba Onanusi Olusegun. Àkíyèsí pàtàkì - Ti ẹ bá ní ohun láti sọ nípa àròkọ yìí, ẹ̀yin náà lè bọ́sí gbàgede. Ìtàn Ìgbésí Ayé Ònkọ̀wé A bí Kọ́lá Akínlàdé ní ọdún 1924, ní ìlú Ayétòrò ní ìpínlẹ̀ Ògùn ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Àwọn òbí rẹ̀ ni Michel Akínlàdé àti Elizabeth Akínlàdé. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Pọ́ọ̀lù mímọ́ ní Ayétòrò. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ yìí ni ó kọjá sí Ìlaròó tí ó sì dá iṣẹ́ tẹ̀wétẹ̀wé sílẹ̀ ńbẹ̀ fúnrarẹ̀ ni ó ka ìwé gba ìwé-èrí G.C. E. ní ilé. Lẹ́yìn tí Kọ́lá Akínlàdé gba ìwé-ẹ̀rí yìí ni ó dá ìwé ìròyàn kan sílẹ̀ tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní ‘Ẹ̀gbádò Progressive Newspaper: Lẹ́yìn èyí ni ó wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi akọ̀wé ìjọba. Ó ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìjọba ìpínlè ìwọ̀-oòrùn àtijọ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Kị́lá Akínlàdé lọ kàwé ní Yunifásítì Ifẹ̀ ní ilẹ̀ Nàìjíríà ó sì tún padà sí ẹnu iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà. Ní ọdún 1976 ni Kọ́lá Akínlàdé fẹ̀yìn tì. Ní ọdún 1980, ó tún gba iṣẹ́ olùkọ́ sí ìbàdàn Boys High School, Ìbàdàn, Nàìjíríà. Ó wá fi ẹ̀yìn tì ní ọdún 1984 Kọ́lá Akínlàdé ní ìyàwó ó sì bí ọmọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ni Kọ́lá Akínlàdé ti kọ. Lára wọn ni Ajá to ń Lépa Ẹkùn, Ọ̣wọ̣̣́ Tẹ Amòokùnṣìkà, Àgbákò nílé Tẹ́tẹ́, Baṣọ̀run Olúyọ̀lé, Ajayi, the Bishop, Chaka, the Zulu, Esther, the Queen, Abraham, The…..Friend of God, Sheu Usman Dan fodio, Òwe àti Ìtumọ̀ rẹ̀, Sàngbá fọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sì tún kópa nínú kíkọ Àsàyàn Ìtàn. Ìwé Àṣírí Amòòkùnṣìkà Tú ní Sókí Ọmọ ilé-èkọ́ ni Dúró Orímóògùnjé. Ó ku Ọdún kan kí ó jáde ìwé mẹ́wàá. Ìyá rẹ̀ kú ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, ìyẹ̀n ni pé ó kú ní ọdún mẹ́ta ṣáájú bàbá rẹ̀. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Bàbá rẹ̀ nígbà tí ó kú. Ikú bàbá rẹ̀ tí ó gbọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ ni o gbé e wálé. Ìyàwó mẹ́rin ni Àkàndé Orímóògùnjẹ́ tí ó jẹ́ ìyá Dúró ti kú, ó ku mẹ́ta. Ọmọ márùn-un ni Àkàńgbé Orímóògùnjé bí Dúró sì ni àgbà gbogbo wọn. Òun ni àkọ́bí. Ìyaa folúké, ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó wọ̀nyí, ni ìríjú àkándé, Orímóògùnjẹ, ìyẹn ni pé òun ni ó fẹ́ran jù. Ìya fólúké yìí ni ó mú kọ́kọ́rọ́ séèfù jáde tí ó ṣí i tí wọn kò sì bá nnkan kan ní ibẹ̀. Ìgbà tí Àkàndé mú owó kẹ́yìn nínú séèfù yìí kí ó tó kú, owó tí ó wà nínú rẹ̀ ju ẹgbàáta náírà (N30,000.00)lọ. Ọ̀gbẹ́ni Ajúṣefínní: Òun ní ó ra kòkó lówó Àkàngbé. Ó sanwo ní 10/2/80. Àṣàkẹ́: Òun ni ó jẹ́rìí sí owó kòkó ti Àkàngbé gbà. Ohun tí ó yani lẹ́nu ni pé Ogóje náírà (N140.00) péré ni wọ́n bá ní abẹ́ ìrọ̀rí Àkàngbé nígbà tí ó kú. Àdùnní: Òun ni ìyá Dúró Orímóògùnjé. Àdùnní ti di olóògbé, ìyẹn nip é ó ti kú. Ọ̀gbẹ́ni Túndé Atọ̀pinpin: Òun ló ní kí Dúró fi ọ̀rọ̀ owó tí ó sọnù lo Olófìn-íntótó. Túnde Atọ��pinpin náà kọ lẹ́tà sí Olófìn-íntótó. Ìdẹ̀ra ni orúkọ ilé-ẹ̀kọ́ àbúrò Túndé Atọ̀pinpin. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni Dúró orímóògùnjẹ́. Ẹ̀gbọ́n Ilẹ́sanmí ni Àdùnní ìyá Dúró Orímóògùnjẹ́. Àgbẹ̀ oníkòkó ni Àkàngbé orímóògùnjẹ́, bàbá Dúró nígbà ayé rẹ̀. Túndé Atọ̀pinpin àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ máa ń sùn ní ilé Àkàngbé nígbà ti wọ́n bá ń lọ sí ìhà Odò Ọya. Dúró Orímóògùnjẹ́ nìkan ni ọmọ tí Àdùnní bé. Ará ìlú Àdùnní ni Olófìn-íntótó, ọmọ Adéṣínà. Túndé Atòpinpin máa ń lọ gbé ojà ní Èkó. Ọkọ̀ ojú omi ni ọjà yìí máa ń bá dé. Olófìn-íntótó, ọmọ olusínà kọ̀wé sí Túndé Atọ̀pinpìn. Àròsọ ni Olófin-íntótó àti ilésanmí ti wokò. Dírẹ́bà wọn ń sáré gan-an ni. Fìlà Olófìn-íntótó tilẹ̀ sí sọ̀nù ní ọ̀nà. Ó dá mọ́tọ̀ dúró ni kí ó tó lọ mú un Nígbà tí wọ́n dé ojà, dírébà jẹ ẹ̀bà, ilésanmí jẹ iyán ó sì ra òòyà ní irinwó náírà (400.00) Ní ọjà, Olófìn-íntótó bá obìnrin kan pàdé. Ó ra ọtí fún un. Obìnrin yìí sì mu ìgò otí kan tán ó sì mu ìkejì dé ìdajì. Ó yẹ kí a sẹ àkíyèsí obìnrin yìí dáadáa nítorí pé òun nì a wá fi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó jí owó Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ jí ní iwájú. Nígbà ti Olófìn-íntótó àti Ilésanmí dé Ilé-Ifè tí wọn ń lọ, ọ̀dọ̀ Àlàó ni wọ́n dé sí. Ilé-Ifẹ̀ ni Àlàó ti ń ta ojà. Àlàó ra obì àti ọtí fún Olófìn-íntótó Olófìn-íntótó mu bíà mẹ́ta. Àlàó ń mu ẹmu lẹ́yìn tí ó jẹun tán Ilésanmú sì ń mu ògógóró. Ọlọ́fìn-íntótó gbádùn láti máà fi ọwọ́ pa túbọ̀mu rẹ̀. Irun tí ó hù sí orí ètè òkè ní ìsàlẹ̀ ibi tí imú wà ni ó ń jẹ́ túbọ̀mu. Àsàkẹ́: Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó Àkàngbé Orímóògùnjẹ́. Gbajímọ̀ ènìyàn ni. Ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ṣùgbọ́n ó dàbí ọmọ ọdún mọ́kànlélógún. Ọ̀mọ̀wé ni. Yéwándé: Ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó Àkàngbé ni òun náà. Kò kàwe ṣùgbọ́n o ní ọ̀yàyà ó sì máa ń ṣe àyẹ́sí ènìyàn. Àlàó: Òun ni Olófin-íntótó àti Ilésanmí dé sí ọdọ rẹ̀. Onígbàgbọ́n ni. Jọ̀ọ́nú ni orúkọ rẹ̀ mìíràn. Ó máa ń gbàdúrà ni alaalé kí ó tó sùn. Ọmọ mẹ́ta ni ó bí. Ní ọjọ́ tí àwọn Olófin-íntótó kọ́kọ́ dé ilé rẹ̀ tí wọ́n ń gbàdúrà ó ní kí gbgbo wọn kọ orin wá bá mì gbé olúwa. Àwọn ọmọ Àlàó kò bá wọn kọ ẹsẹ kejì tí ó sọ wí pé ‘Ọjọ́ ayéè mi ń sáré lọ sópin’. Àsàmú tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Àlàó ni ó ṣe àlàyé fún bàbá rẹ̀ ìdí tí wọn kò ṣe kọ ẹsẹ kejì orin náà. Ó ní orin àgbàlagbà ni. Ilésanmí rọ́ àlà tí ó lá fún Akin Atọ̀pinpin ọmọ Olúṣínà. Ó ní nínú àlá tí òun lá, òún. Rí ẹni tí ó gbé owó ṣùgbọ́n òun kò rí ojú rẹ̀ tí òun fi ta jí. Ẹ jẹ́ kí á ṣe àkíyèsí àwọn nnkan wọ̀nyí tí wọ́n mẹ́nu bà ní orí yìí. Dúró – Òun ni àkọ́bí nínú àwọn ọmọ Orímóògùnjẹ́. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni Fólúkẹ́ - Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ ni òun náà. Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni. Ó ṣẹṣẹ̀ wo kọ́lẹ́jì ni. Ọmọ́wùmí- Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ ni òun náà Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni. Ilé-ẹ̀kọ́ kékeré ni ó wà. Ọládúpọ̀ - - Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjé ni òun náà. Ọmọ ọdún mẹ́fà ni. Ilé-ẹ̀kọ kékeré ni ó wà. Fólúkẹ́, Omówùmí àti Oládípọ̀ jẹ́ ọmọ Yẹ́wándé. Bándélé jẹ́ ọmọ odún méje. Àṣakẹ́ ni ó bíí Yàtọ̀ sí Àkàngbé Orímóògùnjẹ́, Yéwándé nìkan ni ó tún máa ń mu owó nínú séèfù. Àìsàn Orímóògùnjẹ́ kò ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ tí ó fi kú. Ilé Orímóògùnjẹ́ kò ju ilé kẹ́rin lọ sí ilé Àlàó. Nígbà tí àwọn Olófìn-íntótó dé ilé Orímóògùnjẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí. Yéwándé ni ó mú wọn wọlé Kọ́kọ́rọ́ ojú ńlá séèfù yìí kìí ya Orímóògùnjẹ́. Abẹ́ ìrọ̀rí rẹ̀ ni ó wà nígbà tí ó ń ṣàìsàn. Kì í yọ kọ́kọ́rọ́ ojú kékeré séèfù. Àṣàkẹ́ wọlé bá wọn níbi tí wọn ti ń sọ̀rọ̀ níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìwádìí nílé Orímóògùnjẹ́. Wọ́n máa ń há ìlẹ̀kùn yàrá Orímóògùnjẹ́ ṣùgbọ́n wọ́n máa ń fi kọ́kọ́rọ ibẹ̀ há orí ìtérígbà. Ẹnikẹ́ni ní inú ilé ni ó lè mú un ní ibẹ̀ kí ó sì fi sí ilẹ̀kùn Yéwándé ni ó máa ń tọ́jú Orímóògùnjẹ́ lóru nígbà tí ó ń ṣe àìsàn. Àṣàkẹ́ máa ń ràn án lọ́wọ��. Yéwándé àti àwọn ọmọ náà máa ń wá tọ́jú Orímóògùnjẹ́ nígbà ti ó ń ṣàìsàn lọ́wọ́ tí àìsàn rẹ̀ bá ń yọnu. Adékẹ́yẹ ni orúkọ bàbá yéwándé. Ọjà Ajégbémilékè ni Yéwándé fẹ́ lọ ní ọjọ́ tí ọkọ rẹ̀ kú. Àlàó ni ó kó ogóje náírà (N140.00) tí wọ́n bá níbi ìgbèré Orímóògùnjẹ́ fún Yéwándé láti tójú. Orúkọ mìíràn tí Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ tún ń jẹ́ ni Bándélé. Ẹ rántí pé eléyìí yàtọ̀ sí Bándélé orúkọ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ. Ọ̀sanyìnnínbí ni orúkọ oníṣèègùn Orímóògùnjẹ́. Ó ra páànù ìgàn méjìlá ní ọ̀dọ̀ kékeréowó. Èyí sì fẹ́ mí ìfura dání nítorí owó tí ó sonù. Àwọn kan rò pé bóyá òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ tí ó sọnù. Nílé Orímóògùnjẹ́ níbití wọ́n ti ń ṣe ìwádìí, Ọlọ́fìn-íntótó rí ẹ̀já òwú kan tí ó wà lára ọ̀kan nínú àwọn ojú kéékèèkéé inú séèfù ó sì mú un. Gbòngán ni fọláṣadé ìyàwó àfẹ́kẹ́yìn Orímóògùnjẹ́ ń gbé. Ó máa ń lò tó ọjọ́ márùn-ún tàbí ọ̀sẹ̀ kan ní ifẹ̀ ní ilé Orímóògùnjẹ́ kí ó tó padà sí Gbọ̀ngán. Kò bímọ kankan fún Orímóògùnjé. Ó yẹ kí a ṣe àkíyèsí fọláṣadé dáadáa nítorí pé òun ni Olófìn-íntótó ra otí fún ní ọjà tíó mu ìgò ọtí kan àbò. Òun ni a sì rí ní òpin ìwé pé òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ gbé. Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́ ní sítọ́ọ̀. Káyọ̀dé ni orúkọ akọ̀wé rẹ̀. Ó ti tó ọdún mẹ́fà kí Akin Ọlọ́fín-íntótó ọmọ Olúṣínà àti Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́ ti rí ara wọn mọ kí wọn tún tó rí ara wọn yìí. Àbúrò Orímóògùnjẹ́ ni Ilésanmí tí òun àti Olófìn-íntótó jọ wá ṣe ìwádìí ní ilé-Ifè. Ọ̀rẹ́ Orímóògùnjẹ́ ni Ajíṣefínní tí ó ń ta kòkó. Bíọlá ni orúkọ ẹni tí ó ń ta ọtí Lóòótọ́, oníṣèègùn ni Ọ̀sanyìnnínbí síbẹ̀, kò wọ ẹgbẹ́ àwọn Oníṣèègùn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹgbẹ́ ìlera loògùn Ọrọ̀. Awóyẹmí ni orúkọ ẹni tí ó bá àwọn Ọlọ́fìn-íntótó níbi tí wọ́n ti ń gbádùn lọ́dọ̀ Ọmọtóṣọ̀ọ́. Ilésanmí àti Ọlọ́fin-íntótó sọ nípa ara wọn pé àwọn mọ ilẹ̀ tẹ̀ múyẹ́ (Ẹ rántí pé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀lmúyẹ́ ni wọ́n ń ṣe). Ajúṣefínní, ọ̀rẹ́ orímóògùnjẹ́ ni ó bá Orímóògùnjẹ́ ra ilẹ̀ tí ó ń kọ́ ilé sí. A ó rántí pé kòkó ní Ajíṣefínní ń tà. Ọwọ́ Òṣúnlékè ni wọ́n ti r ailẹ̀ tí Orímóògùnjẹ́ fi ń kólé náà. Ẹgbẹ̀ta náírà (N600.00) ni wọ́n ra ilẹ̀ náà. Káyòdé akòwé Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́ sùn ní ẹnu iṣẹ́ Ìgbà tí wọ́n bi í pé kí ló dé tí ó fi sùn ni ó dáhùn pé olè ajẹ́rangbe tí àwọn ń lé ní òru ni kò jẹ́ kí àwọn sùn dáadáa. Ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí pé Oníṣèègùn Ọ̀sanyìnnínbí ni olórí àwọn olè ajẹ́rangbé yìí gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe rí i kà ní iwájú. Ẹran tí ó ń jí gbé yìí wà lára ohun tí ó jẹ́ kí àwọn ènìyàn fura sí Ọ̀sanyìnnínbí pé òun ló jí owó Orímóògùnjẹ́ gbé níbi tí ó tí ń tọ́jú rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe àìsàn. Ẹran mẹ́ta ni wọ́n bá ní ilé àwọn olè wọ̀nyí nítorí pé wọ́n ti jí méjì tẹ́lẹ̀. Nítorí pé Ọ̀sanyìnnínbí jẹ́ ọ̀gá fún àwọn olè wọ̀nyí, wọ́n mú un lọ sí Àgọ́ ọlọ́pàá tí ó wà ní Morèmi ní ilé-Ifè. Nígbà ti Ọlọ́fìn-íntótó gbọ́ pé wọ́n mú Ọ̀sanyìnnínbí sí àgọ́ ọlọ́pàá Morèmi, òun àti Ilésanmí lọ́ sí ibẹ̀. Aago mẹ́fà sí mẹ́jọ ni ọ̀gá ọlọ́pàá máa ń rí ènìyàn ṣùgbọ́n ó gbà láti rí Akin àti Ilésanmí lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rí káàdì Akin. Pópóọlá ni orúkọ ọ̀gá ọlọ́pàá yìí. Ọ̀rẹ́ Akin Olófìn-íntótó, ọmọ Olúṣínà ni. Àbéòkúta ni Pópóọlá wà tẹ̀lẹ̀ kí wọ́n tí wá gbé e wá sí Morèmi ní Ifẹ̀ níbi tí ó ti jẹ́ ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá ibẹ̀. Ó ti tó ọdún mẹ́ta tí ó ti rí Akìn mọ. Pópóọlá bèèrè Túndé Atọ̀pinpin lọ́wọ́ Akin. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n tí wọ́n ti ṣè àlàyé pé ọ̀rọ́ Ọ̀sanyìnnínbí tí wọ́n mú ni ó gbé àwọn wa ni wọ́n ṣe àlàye pé tí ó bá jẹ́ pé òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́, yóò ti ná tó ẹgbẹ̀jọ náírà (N1,600.00) nínú owó náà. Ẹran ti Ọ̀sanyìnnínbí jí gbé ni ó jẹ́ kí wọ́n ní ànfààní láti yẹ ilé rẹ̀ wo. Àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tí àwọn ènìyàn sọ ní orú yìí tí ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí. Ilésanmí ni ó kọrin pé, ‘Iyán lóunjẹ.�� Akin ni ó sọ pé, Ajímutí kìí tí’ Akin náà ni ó sọ pé, ‘Ẹni fojú di Pópó á gba póńpó lórí…’. Orúko Pópíọlá ni ó fi ń ṣeré níbí yìí. Pópóọlá sọ pé, ‘Ẹni tí ó pe tóró, Á ṣẹnu tọ́ńtọ́..’ Ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí pé Àlàó ni oríkì Pópóọlá. Eléyìí yàtò sí Àlàó tí ó tójú àwọn Olófìn-íntótó tí a ti ṣe àkíyèsí rẹ̀ ṣáájú. Nígbà tí wọ́n ló yẹ ilé Ọ̀sanyìnnínbí wò, owó tí wọ́n bá ní ibẹ̀ jẹ́ ọgọ́sàn-án náírà (N180.00) Níní orí yìí, a ó rí òwe, ‘Àfàgò kẹ́yin àparò…’ Ohun tí ó fa òwe yìí ni ẹran tí Ọ̀sanyìnnínbí jí gbé àti ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ní yóò lọ tí ìyàwó rẹ̀ yóò sì ti bímọ kí ó tó dé. Àpatán òwe yìí ni, ‘Afàgò kẹ́yin àparò, ohun ojú ń wá lojú ń rí. Akin Olúṣínà àti Ilésanmí lọ sí ilé Ọ̀sanyìnnínbí. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, òògùn ni Ọ̀sanyìnnínbí wá ṣe. Orí yìí ni a ti mọ ìdí tí Ọ̀sanyìnnínbí fi fẹ́ràn Orímóògùnjẹ́. Ìdí tí ó fi fẹ́ràn rẹ̀ nip é nígbà tí Ọ̀sanyìnnínbí ń ṣe òkú ìyá rẹ̀, ó fún un ní ọgọ́rùn-ún náírà (N100.00) níbi tí kò ti sí ẹni tí ó tún fún un ju náírà márùn-ún lọ. Àlàó tí ó tọ́jú Akin àti Ilésanmí nígbà tí wọ́n dé Ifẹ̀ kò fẹ́ran oògùn ìbílẹ̀ Ọ̀sanyìnnínbí sọ pé Orímóògùnjẹ́ kì í finú tan Àlàó yìí Àwọn ohun tí ó tún yẹ kí á ṣe àkíyèsí ní orí yìí ni ìwọ̀nyí: Awódélé wá kí Ọ̀sanyìnnínbí Àkànbí, àbúrò Aríyìíbí, tí Ọ̀sanyìnnínbí nígbà tí ó ń ṣàìṣàn ní ó dúró fún Ọ̀sanyìnnínbí ní àgọ́ ọlọ́pàá (Ìyẹn ni pé Àkàbí tí Ọ̀sanyìnnínbí wòsàn ni ó dúró fún òun náà) Ní ọjọ́ tí àwọn Ọ̀fíntótó wá sí ilé Ọ̀sanyìnnínbí, nnkan bí agogo mókànlá ni ó wọlé àwọn Òfíntótó sì dé ilé rẹ̀ ní aago méjì kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Nígbà tí Akin Olúṣínà àti Ilésanmí dé ọ̀dọ̀ Ọ̀sanyìnnínbí tí ó rò pé oògùn ni wọ́n wá ṣe ní ọ̀dọ̀ òun, àwọn ẹbọ tí ó kà fún wọn ni ìyá ewúrẹ́ kan, ẹgbẹ̀rún náírà ìgò epo kan, iṣu mẹ́ta àti ìgàn aṣọfunfun kan. Akin Olúsínà mu ẹmu ní ilé Ọ̀sanyìnnínbí Ajéwọlé ni ó ra kòkó lówọ́ Ọ̀sanyìnnínbí. Ẹgbẹ̀fà náírà (N200.00) ni ó gbà ní owó kòkó náà. Àwọn ohun tí ó yẹ kí a ṣe àkíyèsí ní orí yìí ni ìwọ̀nyí: Láti lè mọ iye tí Ọ̀sanyìnnínbí gbà fún kòkó tí ó tà fún Ajéwọlé, ọgbọ́n ni wọ́n fi tan Ọ̀sanyìnnínbí. Wọ́n sọ fún un pé ẹnì kan ń rọbí àti pé yóò nílò oníṣèẹ̀gùn. Ọmọ ọdún mẹ́fà ni Oládiípọ̀. Òun sì ni àbíkẹ́yìn Yéwándé Bándélé jẹ́ ọmọ odún mẹ́jọ. Ọmọ Àṣàkẹ́ ni Jayéjayé kan ni Àṣàkẹ́ máa ń wọ àdìrẹ tàbí borokéèdì ó sì máa ń wọ súwẹ́ta nígbà òtútù. Fawọlé: Ó wà lára àwọn ẹni tí ó wá wo Orímóògùnjẹ́ nígbà tí ara rè kò yá. Nígbà tí Akin Olúsínà ṣe ìwádìí nípa rẹ̀, èsì tí ó rí gbọ́ ni ìwọ̀nyí: Wọ́n ní ìhà sáábó ni Fáwọlé máa ń gbe Tinúkẹ́ ni orúkọ ọmọ rẹ̀. Nípa aṣọ tí ó wọ̀ ní ọjọ́ tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Orímóògùnjẹ́, ẹni kan sọ pé aṣọ sáfẹ́ẹ̀tì pẹ̀lú aṣọ òfì ni ó wọ̀. Ẹni kan sọ pé sán-ányán ni aṣọ tí ó wọ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé àwọn ọmọ́dé kìí tètè gbàgbé nnkan, Akin Olúṣínà ní kí awọ́n bèèrè ìbéèrè nípá Fáwọlé lọ́wọ̀ Fólúkẹ́ àti Bándélé. Fólúkẹ́ sọ pé aṣọ sáfẹ́ẹ̀tì ni ó wọ̀. Ó ní ó dé filà sán-ányán, ó wọ́ bàtà aláwọ̀ funfun ràkọ̀ràkọ̀ Bándélé ni ó bomi fún Fáwọlé ní ọjọ́ tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Orímóògùnjẹ́. Folúkẹ́ ní ojoojúmọ́ ni Ọ̀sányìnnínbí máa ń wá sọ́dọ̀ Orímóògùnjẹ́ nígbà tí Orímóògùnjẹ́ ń sàìsàn ó sì máa ń dúró di ìgbà tí wọ́n bá ń pèrun alẹ́ kí ó tó kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Folúkẹ́ ní òun rí nnkan kan bí ológbò ní àpò rẹ̀ ni ọjọ́ kan. Àlàó kò gbọ́ nípa ẹni tí ó ń fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò nítorí pé ó lọ sí ibì òkú ìyá Báyọ̀ ní ọjọ́ náà. Ìyá Bándélé ni ẹni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dan séèfù wò náà Orímóògùnjẹ́ kò sọ ọ̀rọ̀ eni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò yìí fún Àlàó. Yéwándé náà kò sọ fún un. 9. Igba náírà (N200.00) ni wọ́n bá ní ilé Àṣàkẹ́, ìyẹn ìyá Bándélé nígbà tí àwọn Akin Ọlọ́fìn-íntótó yẹ ilé rẹ̀ wò. Ẹni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè ni Àṣàkẹ́ ìyá Bándélé. folúkẹ́ ni ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé Àṣàké ń fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò. Àṣàkẹ́ máa ń kanra mọ́ ọmọdé. Aṣọ òfì ni Yéwándé wọ̀ nígbà tó wọ́n ń ṣe ìwádìí yìí torí òtútù. Ọjọ́ kejì ọjà Ajágbénulékè ni Àṣàkẹ́ rí kọ́kọ́rọ́ tí ó fi dán séèfù wò nínú yàrá rẹ̀. Àlàá, Àkin àti Ilésanmí fi kọ́kọ́rọ́ náà dán séèfù wò, kò sí i. Lẹ́yìn ìwádìí ti ọjọ́ yìí, Akin Ọlọ́fìn-íntótó àti ilésanmí padà sí Ìbàdàn. Ní ibi tí Akin ti dá mọ́lò dúró nígbà tí o fẹ́ ẹran ìgbẹ́ ni bàbá alágbẹ̀dẹ kan ti sọ fún ọmọ kan pé kí ó wò ọkọ̀ náà. Kọ́lá ni orúkọ ọmọ yìí. Orí yìí ní wọ́n ti wá mọ orúkọ ọmọge tí Akin Olúṣínà ra ọtí fún nígbà tí wọ́n ń lọ sí Ifẹ̀ tí a ti mẹ́nu bà ṣáájú. Orúkọ ọmọge yìí ni fìlísíà Olówólàgbà. A ó rí i ní iwájú pé filísíà Olówólàgbà yìí ni orúkọ mìíràn fún ìyàwo Orímóògùnjẹ́ tí ó jí owó Orímóògùnjé gbé. Akin àti Ilésanmí wá filísíà yìí lọ sí pètéèsì aláwò pupa rúsúsúsú. Kọ́lá ni ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ilé yìí. Akin àti Ilésanmí sun ọ̀dọ Fìlísíà mọ́jú. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n rí Pópóọlá. Ó gbé wọn dé màpó. Akin lọ gbowó ní bànkì. Òun àti Ilésanmí ni wọ́n jọ lọ. Ní bánkì, wọ́n pàdé Kọ́lá. Ẹnu rẹ̀ ni wọ́n ti gbọ́ pé Bínpé àbúrò fìlísíà fẹ́ ṣe ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngán. Pópóọlá gbé Akin, Ilésanmí àti Kọ́lá. Ní ọ̀nà, ní ibi tí alágbẹ̀dẹ́ ti fi Kọ́lá sí ọkọ̀ ní ìjelòó, wọ́n rí àwọn méjì tí wọ́n ń jà Ògúndélé ni orúkọ alágbẹ̀dẹ yìi. Òun ni ó ń bá Jìnádù jà. Wọ́n gbá Adénlé tí ó fẹ́ là là wọ́n ní ẹ̀sẹ̀ nínú. Pópóọlá tí ó jẹ́ ọlọ́pàá ni ó pàṣẹ pé kí wọn dá ọwọ́ ìjà dúró tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tí ó fa ìjà tí Ògúndélé àti Jinádù ń jà ni pé Ògúndélé tí ó jé alágbẹ̀dẹ rọ kọ́kọ́rọ́ kan fún jìnádù ní múrí mẹ́ta (#60), Jìnádù san Múrí kan (#20) níbẹ̀ ó ku múrí méjì (#40). Ògúndélé bínú nítorí pé Jìnádù kò tètè san múrí méjì tí ó kì. Jìnádù bínú nítorí pé ó sọ pé Ògúndélé sin òun ní owó ní àárí àwùjọ. Jìnádù sọ pé Ògúndélé fi òrùkọ ẹ̀rẹ na òun. Nígbà tí Kọ́là sọ̀ kalẹ̀ tí ó ń lọ, ó gbàgbé àpò rẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n dá a padà fún un. Nígbà tí Ain àti Ilésanmí ti Ìbàdàn tí wọ́n ti ń bọ̀ dé Ilé-Ifẹ̀, wọ́n lọ sí ilé fáwọlé Nígbà tí Orímóògùnjẹ́ ń ṣàìsàn lọ́wọ́ tí fọláṣadé 9tí àwa tún mọ̀ sí fìlísíà) wá sí Ifẹ̀, ó lò tó ọjọ́ mẹ́ta dípò méjì tí ó máa ń lò tẹ́lẹ̀. Ìpàdé ọmọlẹ́bí tí wọ́n fẹ́ ṣe gan-an ni ó tèlè mú un padà. Yàtọ̀ sí ìgbà tí ìnáwó pàjáwùrù bá wà ọjọ́ karùn-ún kànùn-ún ni Orímóògùnjẹ́ máa ń mú owó nínú séèfù rẹ̀ nígbà tí ó wà láyé. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, Yéwándé máa ń bá Orímóògùnjẹ́ mú owó nínú séèfù rẹ̀ ṣùgbọ́n ó tó oṣù kan sí ìgbà tí Orímóògùnjẹ́ tó kú tí ó ti rán an mú owó nínú rẹ̀ gbèyìn. Ọjọ́ ọjà ni ọjọ́ tí Orímóògùnjẹ́ máa ń mú owó nínú séèfù rẹ̀ máa ń bọ́ sí. Ọjọ́ kẹ́rin tí Orímóògùnjẹ́ mú owó kẹ́yìn nínú séèfù rẹ̀ ni ó kú. Ìyẹn ni pé ọjà dọ̀la ni ó kú Orímóògùnjẹ́ máa ń fún àwọn ìyàwó rẹ̀ ní owó-ìná tí ó bá ti mówó. Níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìwadìí yìí, Akin Olúṣínà ń fi ataare jobì. Túndé Atọ̀pinpin ní kí àwọn yẹ yàrá Fọláṣadé wò. Ìsòrí kọkànlá yìí ni ó ti hàn gbangba pé Fọláṣadé, ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó Orímóògùn ni ó jí owó rẹ̀ gbé. Ó ní ìdí tí òun fi jí owó náà gbé nip é òun kò bímọ fún Orímóògùnjẹ́ òun kò sì fẹ́ kì tòun ó gbé sílé rẹ̀ nítorí pé ọmọ tì obìnrin bá bí fún ọkọ ni wọ́n fi máa ń pín ogún ọkọ náà ní ilẹ̀ Yorùbá. Fọláṣadé ni ó yí orúkọ padà tí ó di fìlísíà. Òun náà ni ó lọ rọ kọ́kọ́rọ́ lọ́dọ̀ bàbá àgbẹ̀dẹ tí Àṣàkẹ́ fi dán séèfù wò. Àwọn Èdá-Ìtàn Akin Olúṣínà Òun ni wọ́n máa ń pè ní Akin Ọlófìn-íntótó, ọmọ Olúṣínà. Òun ni ó ṣe ìwádìí owó tí ó sọnù. Àròsọ ni ó ti wọkọ̀ lọ sí Ifẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí owó náà. Fìlà rẹ̀ sí bọ́ sílẹ̀ nínú mọ́tò tí ó wọ̀. Dírẹ́bà ọkọ̀ yìí kò mọ ọkọ̀ wà dáadáa. Akin Olúṣíná fẹ́ràn ẹran ìgbẹ́. Ó máa ń mutí. Ó máa ń jobì tó fi ataa sínú rẹ̀. Ó ní túbọ̀mu ó sì máa ń fi ọwọ́ pa á. Ó ṣe wàhálà púpọ̀ kí ó tó mọ̀ pé Fọláṣadé tí ó tún ń jẹ́ filísíà nì ó jí owó Orímóògùnjẹ́ kó. Foláṣádé: Òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ kó. Kò bímọ fún Orímóògùnjẹ́. Ìdí nì yí tí ó fi jí owó rẹ̀ gbé. Ó ní kí ti òun má bàa jẹ́ òfo nílé Orímóògùnjẹ́ ni ó jẹ́ kí òun jí owó rẹ̀ gbé. Fọláṣadé náà ni ó yí orúkọ padà sí fìlísíà Olówálàgbà. Orúkọ yìí ni ó si fi lọ fi owó pamọ́ sí bánkì. Gbòngán ni ó ń gbé ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi fìlísíà, ó ní ilé sí Ibadan. Gẹ́gẹ́ bíi fìlísíà, Ọ̀gá ni ó jẹ́ fún Kọ́lá Òwú ara súwẹ́tà rẹ̀ tí ó já bọ́ síbi séèfù wà lára ohun tí ó ran Akin Olúṣínà lọ́wọ́ láti rí i mú. Ìwé ìfowópamọ́ rẹ̀ tí Akin Olúṣínà rí lọ́wọ́ Kọ́lá náà tún wà lára ohun tí ó ran Akin Olúṣínà lọ́wọ́. Fọláṣadé wà lára àwọn tí wọ́n bí séèfù lójú rẹ̀ ní ilé Orímóògùnjẹ́ tí wọn kò bá nnkan kan níbẹ̀. Kò sì jẹ́wọ́ pé òun ni òun kó owó tí ó wà níbẹ̀. Ó máa ń ti Gbọ̀ngán wá sí Ifẹ̀. Òun ni ìyàwó àfẹ́kẹ́yìn foún Orímóògùnjẹ́. Tí ó bá wá láti Gbọ̀ngán, ó máa ń lò tó ọjọ́ márùn-ún ní Ifẹ̀ tàbí ọ̀sẹ̀ kan. Ilé oúnjẹ ni Akin àti Ilésanmí ti kọ́kọ́ pàdé rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó jiyán tán ní ilé olóúnjẹ yìí, ó mu ìgò otí kan àti àbọ̀ nínú ọtí tí Akin Olúṣínà rà. Àkàngbé Ọrímóògùnjẹ́: Òun ni wọ́n jí owó rẹ̀ gbé tí Akin Olúṣínà wá ṣe ìwádìí rẹ̀. Àìsàn tí ó ṣe é tí ó fi kú kò ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ. Abẹ́ ìrọ̀rí rẹ̀ ni kọ́kọ́rọ́ ojú ńlá séèfù rẹ̀ máa ń wà. Inú séèfù yìí nì ó máa ń kó owó sí. Kìí yọ àwọn kọ́kọ́rọ́ ojú kékeré séèfù yìí. Tí wọ́n bá ti ilèkùn yàrá rẹ̀, wọ́n máa ń fi kọ́kọrọ́ há orí àtérígbà níbi tí ẹnikẹ́ni ti lè mú un. Orúkọ múràn tí ó ń jẹ́ ni Bándélé. Ogóje náírà (#140), péré ni wọ́n bá nígbà tí ó kú tán. Kí ó tó kú ó ti ra ilẹ̀ tí yóò fi kọ́lè. Ajíṣafínní ni ó bá a dá sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ tí ó rà náà. Owó Òṣúnlékè ni ó ti rà á. Ẹgbàáta náírà (#6,000) ni ó ra ilẹ̀ náà. Dúró ni àkọ́bí ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́. Ilé-ẹ̀kọ́ girama ni ó wà. Ọdún kan ni ó kù kí ó jáde. Òun ni ó kọ ìwé sí Akin Olúṣínà pé kí ó wá bá òun wádìí owó bàbá òun tí wọn kò rí mọ́. Àdùnní ni orúkọ ìyá rẹ̀ òun nìkan ni ó sì bí fún bàbá rẹ̀. Àdùnní yìí tí kú ní ọdún mẹ́ta ṣáájú bàbá rẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) nì Dúró. Àbúrò mẹ́rin ni ó ní. Àwọn náà ni Àdùkẹ́, Ọmọ́wùmí, Oládípò àti Bándélé. Àdùnní: Àdùnní ni ìyàwó tí Orímóògùnjẹ́ kọ́kọ́ fẹ́. Ó kú ní ọdún mẹ́ta sáájú ọkọ rẹ̀. Òun ni ó bí Dúró fún Orímóògùnjẹ́. Ẹ̀gbọ́n ni ó jẹ́ fún Ilésanmí. Ọmọ ìlú kan náà nì òun àti Akin Olúṣínà. Ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ẹ̀kọ́ kan pàtàkì tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Kò sí ẹ̀dá alààyè tó dá wà láì ní Olùbátan tàbí alájogbé. Orísirísi ènìyàn ló parapọ̀ di àwùjọ-bàbá, ìyá, ará, ọ̀rẹ́, olùbátan ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí ìyá ṣe ń bí ọmọ, tí bàbá ń wo ọmọ àti bí ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ ṣe ń báni gbé, bẹ́ẹ̀ ni ìbá gbépọ̀ ẹ̀dá n gbòòrò si. Gbogbo àwọn wọ̀nyí náà ló parapọ̀ di àwùjọ-ẹ̀dá. Àti ẹ̀ni tí a bá tan, àti ẹni tí a kò tan mọ́, gbogbo wa náà la parapọ̀ di àwùjọ-ẹ̀dá. Ní ilẹ̀ Yorùbá ati níbi gbogbo ti ẹ̀dá ènìyàn ń gbé, ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ṣe pàtàkì púpọ̀. Bí ẹnìkan bá ní òun ò bá ẹnikẹ́ni gbé, tí kò bá gbé nígbó, yóó wábi gbàlọ. Ṣùgbọ́n, àwa ènìyàn lápapọ̀ mọ ìwúlò ìbágbépọ̀. Orísirísi ànfàní ni ó wà nínú ìbágbépọ̀ ẹ̀dá. Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn bá n gbé papọ̀, ó rọrùn lati jọ parapọ̀ dojú kọ ogun tàbí ọ̀tẹ́ tí ó bá fẹ́ wá láti ibikíbi. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní àjòjì ọwọ́ kan ò gbẹ́rù dórí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ló ṣe rí fún àwùjọ-ẹ̀dá. Gbígbé papọ̀ yìí máa ń mú ìdádúró láì sí ìbẹ̀rù dání nítorí bí òṣùṣù ọwọ̀ ṣe le láti ṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwùjọ tó fohùn ṣọ̀kan. Èyí jẹ́ oun pàtàkì lára ànfàní tó wa nínú ìṣọ̀kan nínú àwùjọ-ẹ��dá. Nídà kejì, bí ọ̀rọ̀ àwùjọ-ẹ̀dá ba jẹ́ kónkó-jabele, ẹ̀tẹ́ àti wàhálà ni ojú ọmọ ènìyàn yóó máa rí. Nítorí náà, ó dára kí ìṣọ̀kan jọba ni àwujọ-ẹ̀dá. Ìdàgbàsókè tí ó máa ń wà nínú àwùjọ kò sẹ̀yìn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ bí àti ránmú un gángan ò ti sẹ̀yìn èékánná. Ó yẹ kí á mò pé nítorí ìdàgbàsókè ni ẹ̀dá fi ń gbé papọ̀. Bí igi kan ò ṣe lè dágbó ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnìkan ò lè dálùúgbé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló máa ń dá Ọgbọ́n jọ fún ìdàgbàsókè ìlú. Bí Ọgbọ́n kan kò bá parí iṣẹ́, Ọgbọ́n mìíràn yóó gbè é lẹ́yìn. Níbi tí orísirísi ọgbọ́n bá ti parapọ̀, ìlọsíwájú kò ní jìnnà si irú agbègbè bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn nnkan wọ̀nyí jẹ́ ànfàní tó wà ní àwùjọ-ẹ̀dá tí kò sì ṣe é fi sílẹ̀ láì mẹ́nu bà. Nínú ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá, a tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìsòro tó ń kojú ìbágbépọ̀ ẹ̀dá. Kò ṣe é ṣe kó máa sì wàhálà láwùjọ ènìyàn. A kò lè ronú lọ́nà kan ṣoṣo, nítorí náà, ìjà àti asọ̀ máa ń jẹ́ àwọn nnkan tí a kò lè ṣàì má rì í níbi ti àwọn ènìyàn bá ń gbé. Wàhálà máa ń fa ọ̀tẹ̀, ọ̀tẹ̀ ń di ogun, ogun sì ń fa ikú àti fífi dúkàá sòfò. Àwọn nnkan wọ̀nyí jẹ́ ara àwọn ìṣòro tó n kojú àwùjọ-ẹ̀dá. Kò sí bí ìlú tàbí orílè-èdè kan kò se ní ní ọ̀kan nínú àwọn àwọn ìṣòro wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, a gbódò mọ̀ wí pé awọn ànfàní àti awọn ìṣòro wọ̀nyí ti wà láti ìgbà pípé wá. Tí a bá wo àwọn ìtàn àtijọ gbogbo, a ó ri pé gbogbo àwọn nnkan wònyí kò jẹ́ tuntun. Ọgbọ́n ọmọ ènìyàn ni ó fi ṣe ọkọ̀ orí-ìlẹ, ti orí-omi àti ti òfúrifú fún ìrìnkèrindò tí ó rọrùn. Àwùjọ-ẹ̀dá ti ṣe àwọn nnkan dáradára báyìí náà ni wọ́n ń ṣe àwọn ohun tí ó lè pa ènìyàn lára. Fún àpẹẹrẹ, ìbọn àti àdó-olóró. Àwọn ohun ìjà wọ̀nyí ni wọ́n lò ní ogun àgbájé kìnní tí o wáyé ní Odun 1914 sí 1918 àti ti èkejì ní odún 1939 sí 1945 Gbogbo àwọn nnkan wọ̀nyí ló ti wà tí ó sì tún wà síbè di òní. Lákòótán, ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ẹ̀kọ́ tó lárinrin. Ohun kan tí a gbọ́dọ̀ mọ̀ nip é, kò ṣe é ṣe kí ẹ̀dá máa gbe ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Ìdí ni pé gbígbé papọ̀ pẹ̀lú ìsọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ló lè mú ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbà-sókè wá Adìẹ funfun kò mọ ara rẹ̀lágbà Ọbẹ̀ kìí gbé inú àgbà mì À ń pe gbẹ́nàgbẹ́nà ẹyẹ àkókó ń yọjú Díẹ̀ díẹ̀ nimú ẹlẹ́dẹ̀ẹ́ fi ń wọgbà Ilé ọba tójó ẹwà ló bùsi Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà Ìjèbú-Jèṣà je ilu ni ile Naijiria ati oluilu agbegbe ijoba ibile Oriade ni Ipinle Osun. Oríṣìíríṣìí ìtàn àtẹnudẹ́nu ni a ti gbọ́ nípa ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ọ̀rọ̀ òkèèrè sì nìyí, bí kò bá lé yóò dín. Ọ̀kan nínú àwọn ìtàn náà sọ pé: Ọwà Iléṣà kìíní Ajíbógun àti Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà kìíni, Agírgírì jẹ́ tẹ̀gbọ́n tábúrò. Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ni ẹ̀gbọ́n tí Ọwá sì jẹ́ àbúrò. Bákan náà, tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni ìyá tí ó bí wọn. Láti ọmọomún ni ìyá Ajíbógun Ọwá Iléṣà ti kú Ìyá Agígírì tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ ló wò ó dàgbà, ọmún rẹ̀ ló sì mún dàgbà. Nípa bẹ́ẹ̀ Ọwá Ajíbógun àti Agígírì jọ dàgbà pọ̀. Èyí ló mú kí wọn di kòrí-kòsùn ara wọn láti kékeré wá, wọn kí í sì í yara wọn bí ó ti wú kí ó rí. Ìgbà tí wọ́n dàgbà tán, tí ó di wí pé wọ́n ń wá ibùjókòó tí wọn yóò tẹ̀dó, àwọn méjèéji-Agígírì àti ajíbogun yìí náà ló jìjọ dìde láti Ilé-Ifẹ. Wọn wá sí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣa láti dó sí kí wọn lè ni àyè ijọba tiwọn. Ajíbogun dúró níbi tí a ń pè ní Iléṣa lónìí yìí, òun sì ni Ọwá Iléṣà kìíní. Agígírì rìn díẹ̀ síwájú kí ó tó dúró. Lákòókó tí ó fi dúró yẹn, ó rò wí pé òun ti rìn jìnnà díẹ̀ sí àbùrò òun kò mọ̀ wí pé nnkan ibùsọ̀ mẹ́fà péré ni òun tí ì rín. Ṣùgbọ́n, lọ́nà kìíní ná, kò fẹ́ rìn jìnnà púpọ̀ sí àbúrò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ìpinnu wọn pé àwọn kò gbọdọ̀ jìnná sára wọn bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn méjèè jì kò jọ fẹ́ gbé ibùdó kan náà. Lọ́nà kejì, ò lè jẹ́ wí pé bóyá nítorí pé ẹsẹ̀ lásán tó fi rín nígbà náà tàbí nítorí pé aginjù tó fi orí là nígbà náà ló ṣe rò wí pè ibi tí òun ti rìn ti nàsẹ̀ díẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àbúrò òun lo ṣe dúró ni ibi tí a ń pè ní Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lónìí. Kì wọn tó kùrò ni Ifẹ̀, wọn mú àádọta ènìyàn pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ìgbà tí wọ́n dé Iléṣà ti Ajíbógun dúró, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fún un ní ọgbọn nínú àádọ́tà ènìyàn náà. Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọn, òun lè dáàbò bo ara òun, ò sí kó ogún tó kù wá sí ibùdo rè ni Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà. Ìdí nìyí tí a fi ń ki ìlú náà pé; “Ijẹ̀ṣà ọgbọ̀n Ijẹ̀bú ogún É sìí bó ṣe a rí Kógún a parẹ́ mọ́gbọ̀n lára” Ìtàn míràn sọ fún wa pé ọmọ ìyá ni Agígírì àti Ajíbógun ni Ilé-Ifẹ̀. Ajíbógun ló lọ bomi òkun wá fún bàbá wọn - ọlọ́fin tí ó fọ́jú láti fi ṣe egbogi fún un kí ó lè ríran padà ó lọ, Ó si bọ̀. Ṣùgbọ́n kí ó tó dé àwọn ènìyàn pàápàá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rò wí pé ó ti kú, wọ́n sì ti fi bàbá wọn sílẹ̀ fún àwọn ìyàwó rẹ fún ìtọ́jú. Kí wọn tó lọ, wọ́n pín ẹrù tàbí ohun ìní bàbá wọn líifi nnkan kan sílẹ̀ fún àbúro wọn – Ajíbógun. Ìgbà tí ó dé, ó bu omi òkun bọ̀, wọ́n lo omi yìí, bàbá wọn sì ríran. Ojú Ajíbógun korò, inú sì bi pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti fi bàbá wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì kó ohun ìnú rẹ̀ lọ. bàbá wọn rí i pé inú bí i, ó sì pàrọwà fún un. “Ọmọ àlè ní í rínú tí kì í bí, ọmọ àlè la ń bẹ̀ tí kì í gbọ́” báyìí ló gba ìpẹ́ (ẹ̀bẹ̀) bàbá rẹ̀. ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ fun un ní idà kan – Idà Ajàṣẹ́gun ni, ó ni kí ó máa lé awọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ pé ibikíbi tí ó bá bá wọn, kí ọ bèèrè ohun ìní tirẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ pa wọ́n. Ajíbógun mú irin-àjò rẹ̀ pọ̀n, níkẹhìn ó bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìní padà lọ́wọ́ wọn. Pẹ̀lú iṣẹ́gun lórí àwọn arákùnrin rẹ̀ yìí, kò ní ìtẹ́lórùn, òun náà fẹ́ ní ibùjókòó tí yóò ti máa ṣe ìjọba tirẹ̀. Kò sí ohun tí ó dàbí ọmọ ìyá nítorí pé okùn ọmọ ìyà yi púpọ̀. Agígírí fẹ́ràn Ajíbógun ọwá Obòkun púpọ̀ nítorí pé ọmọ ìyá rẹ̀ ni. Bàyìí ni àwọn méjèèjì pèrò pọ̀ láti fi Ilé - Ifẹ̀ sílẹ̀ kí wọn sì wá ibùjókòó tuntun fún ara wọn níbi tí wọ́n yóò ti máa ṣe ìjọba wọn. Itán sọ pé Ibòkun ni wọ́n kọ́kọ́ dó sí kí wọn tó pínyà. Ọwá gba Òdùdu lọ, Ọna Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà sì gba Ilékéte lọ. Ó kúrò níbẹ̀ lọ si Ẹẹ̀sún. Láti Eẹ̀sún ló ti wá sí Agóró: Agóró yìí ló dúró sí tí ó fi rán Lúmọ̀ogun akíkanju kan patàki nínú àwọn tí ó tẹ̀ lé e pé kí ó lọ sì iwájú díẹ̀ kí ó lọ wo ibi tí ilẹ̀ bá ti dára tí àwọn lè dó sí. Lúmọ̀ogun lẹ títí bí ẹ̀mí ìyá aláró kò padà. Àlọ rámirámi ni à ń rí ni ọ̀ràn Lúmọ̀ogun, a kì í rábọ̀ rẹ̀. Igbà ti Agígírì kò rí Lúmọ̀ogun, ominú bẹ̀rẹ̀sí í kọ́ ọ́, bóyá ó ti sọnù tàbí ẹranko búburú ti pá jẹ. Inú fun ẹ̀dọ̀ fun ni ó fi bọ́ sọ́nà láti wá a títí tí òun ó fi rí i. Ibi tí wọ́n ti wá a kiri ni wọ́n ti gbúròó rẹ̀ ni ibì kan tí a ń pè ní Òkèníṣà ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lonìí yìí. Iyàlẹnu ńlánlà lọ́ jẹ́ fún Agígírì láti rí Lúmọ̀ogun pẹ̀lù àwọn ọdẹ mélòó kan, Ó ti para pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọdẹ wọ̀nyí ó sì ti gbàgbé iṣẹ́ tí wọ́n rán an nítorí ti ibẹ̀ dùn mọ́ on fún ọwọ́ ìfẹ́ tí àwọn ọdẹ náà fi gbà á. Inú bí Agígírì a sì gbé e bú. Ṣùgbọ́n isàlẹ̀ díẹ̀ ni òun náà bá dúro sí. Eléyìí ni wọ́n ṣe máa ń pe Òkònísà tí wọ́n dó sí yìí ní orí ayé. Wọ́n á ní “Òkènísà orí ayó”. Agbo ilée Bajimọn ní Òkè -Ọjà ni Agígírì sọ́kọ́ fi ṣe ibùjókòó. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́jìn èyí ni ó bá lọ jà ogun kan, ṣùgbọ́n kí ó tó padà dé, ọmọ rẹ̀ kan gbà òtẹ́ ńlá kan jọ tí ó fi jẹ́ wí pé Agígírì kò lè padà sí ilée Bajimọ mọ́. Ìlédè Agígírì kọjá sí láti lọ múlẹ̀ tuntun tí ó sì kọ̀lé sí Ilédè náà ní ibi tí Aàfin Ọba Ijẹ̀bú-jẹ̀ṣà wà títí di òní yìí. Ó jókòó nibẹ̀, ó sí pe àwọn tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí wọ́n múra láti ibé ogun ti ọmọ rẹ̀ náà títí tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀. Nikẹhìn, ọmọ náà túnúnbá fún bàbá rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. “Ojú iná kọ́ ni ewùrà ń hurun”. Ẹnu tí ìgbín sì fib ú òrìṣà yóò fi lọlẹ̀ dandan ni” Ọmọ náà tẹríba fún bàbá rẹ́ ó sì mọ̀ àgbà légbọ̀n-ọ́n. Ìtàn míràn bí a ṣe tẹ Ijẹ̀bù-Jẹ̀ṣà dò àti bí a ṣe mọ̀ ọ́n tàbí sọ orúkọ rẹ̀ ní Ìjẹ̀bí-Jẹ̀ṣà ni ìtàn àwọn akíkanjú tàbí akọni ọdẹ méje tí wọ́n gbéra láti Ifẹ láti ṣe ọdẹ lọ. Wọ́n ṣe ọdẹ títí ìgbà tí wón dé ibi kan, olórí wọ́n fi ara pa. Wọ́n pẹ̀rẹ̀sì í tọ́júu rẹ̀ ìgbà tí wọ́n ṣe àkíyèsí wí pé ọgbẹ́ náà san díẹ̀, wọ́n tún gbéra, wọ́n mù ọ̀nà-àjò wọn pọ̀n Igbà tí wọ́n dé ibi tí a ń pè ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lónìí yìí ni ẹ̀jẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀sí í sàn jáde láti ojú ọgbẹ́ ọkùnrin náà. Wọ́n bá dúró níbẹ̀ láti máa tọ́jú ogbà náà, wọ́n sì dúró pẹ́ dìẹ̀. Nígbẹ̀hìn, wọ́n fi olórí wọ́n yìí síbẹ̀, wọ́n pa àgó kan síbẹ̀ kí ó máa gbé e. Ìgbà tí àwọn náà bá ṣọdẹ lọ títí, wọn a tún padà sọ́dọ̀ olórí wọn yìí láti wá tójùu rẹ̀ àti láti wá simi lálẹ́. Wọ́n ṣe àkíyèsí pé ìbẹ̀ náà dára láti máa gbé ni wọ́n bá kúkú sọbẹ̀ dilé. Ìgbà tí ara olórí wọn yá tán, tí wọ́n bá ṣọdẹ lọ títí, ibẹ̀ ni wọ́n ń fàbọ̀ sí títí tí ó fi ń gbòrò sí i. Orúkọ tí Olórí wọn –Agígírì sọ ibẹ̀ ni IJẸLÚ nítorí pe ÌJẸ̀ ni Ìjẹ̀sà máa ń pe Ẹ̀JẸ̀. Nigbà tí ìyípadà sì ń dé tí ojú ń là á sí i ni wọ́n sọ orúkọ ìlú da ÌJẸ̀BÚ dípò Ìjẹ̀bú tí wọ́n ti ń pè tẹ́lẹ̀. Agígírì yí ni Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà kiíní, àwọn ìran ọlọ́dẹ méje ìjọ́sí ló di ìdílé méje tí ń jọ́ba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà títí di òní. Ṣùgbọ́n Ijẹ̀bú - Ẹrẹ̀ ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń pe ìlú yìí rí nítorí ẹrẹ̀ tí ó ṣe ìdènà fún awọn Ọ̀yọ́. Ó ń gbógun ti ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà nígbà kan. Ní ìlú náà ẹrẹ̀ ṣe ìdíwọ́ fún àwọn jagunjagun Ọ̀yọ́ ni wọ́n bá fi ń pe ìlú náà ni Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀. Ní ọdún 1926 ni ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí “Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà Progressive Union” yí orúkọ ìlú náà kúrò láti Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀ sí Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà nítorí pé ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni Ìjẹ̀bú yìí wa. A níláti tọ́ka sí i pé Ìjẹ̀bú ti Ìjẹ̀ṣà yí lè ní nnkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bu ti Ìjẹ̀bù –Òde. Bí wọ́n kò tilẹ̀ ní orírun kan náà. Ìtàn lè pa wọ́n pọ̀ nipa àjọjẹ́ orúkọ, àjọṣe kankan lè má sí láàárin wọn nígbà kan ti rí ju wí pé orúkọ yìí, tó wu Ògbóni kìíní Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà nígbà tí ó bá àbúrò rẹ̀ Ajíbógun lọ bòkun, wọ́n gba ọ̀nà Ìjẹ̀bú-Òde lọ. Ibẹ̀ ló gi mú orúkọ yìí bọ̀ tí ó sì fi sọ ilú tí òun náà tẹ̀dó. Nínú àwọn ìtàn òkè yí àwọn méjì ló sọ bí a ṣe sọ ìlú náà ní Ijẹ̀bú ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pé a lè gba ti irúfẹ́ èyí tí ó sọ pé Ìjẹ̀bú – Òde ni Ọba Ijẹ̀bú Jẹ̀ṣà ti mú orúkọ náà wá ní eléyìí ti ó bójú mi díẹ̀. Orúkọ yìí ló wú n tí ó sì sọ ìlú tí òun náà tẹ̀dó ní orúkọ náà. Orúkọ oyè rè ni Ògbóni. Itán sọ fún wa pé ibẹ̀ náà ló ti mú un bọ̀. Gẹ́gẹ́ bi ìtàn àtẹnudẹ́nu, oríṣìíríṣìí ọ̀ná ni a máa ń gbà láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀, Ṣùgbọ́n ó kù sọ́wọ́ àwọn onímọ̀ òde òní láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìtàn wọ̀nyí kí a sì mú eléyìí tí ó bá fara jọ ọ̀ọ́tó jù lọ nínú wọn. Nipa pé tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni Ọwá Iléṣà àti Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ láti àárọ̀ ojọ́ wà yìí, sọ wọ́n di kòrí – kòsùn ara wọn. Wọ́n sọ ọ́ di nnkan ìnira làti ya ara kódà, igbín àti ìkarahun ni wọ́n jẹ́ sí ara wọn. Ṣé bí ìgbín bá sì fà ìkarahun rẹ̀ a sẹ̀ lé e ni a máa ń gbọ́. Ìgbà tí ó di wí pé àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò yí máa fi Ifẹ́ sílẹ̀, ìgbà kan náà ni wọ́n gbéra kúrò lọ́hùnún, apá ibì kan náà ni wọ́n sì gbà lọ láti lọ tẹ̀dó sí. Ọ̀rọ̀ wọn náà wà di ti ajá tí kì í lọ kí korokoro rẹ̀ gbélẹ̀. Ibi tí a bá ti rí ẹ̀gbọ́n ni a ó ti rí abúrò. Àjọṣe ti ó wà láàárìn wọ́n pọ̀ gan-an tí ó fi jẹ́ wí pé ní gbogbo ìlẹ̀ Ijẹ̀ṣà, Ọba Ijẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jọ ní àwọn nnkán kan lápapọ̀ bẹ́ẹ̀ náà si ni àwọn ènìyàn wọn. Tí Ọwá bá fẹ́ fi ènìyàn bọrẹ̀ láyé àtijọ́, Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ gbọ́ nípa rẹ̀. Tí Ọwá bá fẹ́ bọ̀gún, ó ní ipa tí Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ kó níbẹ̀, ó sì ní iye ọjọ́ tí ó gbọ́dọ̀ lò ní Ilẹ̀ṣà. Ní ọjọ́ àbọlégùnún, ìlù Ọba Ìjẹ̀bu-Jẹ̀ṣà ni wọ́n máa n lù ní Ilẹ́ṣà fún gbogbo àwọn àgbà Ìjẹ̀ṣà làti jó. Nìgbà tí Ọba Ìjẹ̀bù -Jẹ̀ṣà bá ń bọ̀ wálé lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí ó ti lọ̀ ni Ilẹ́ṣà fún ọdún ògún, ọtáforíjọfa ni àwọ̀n ènìyàn rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ pàdé rẹ̀. Idí nìyí tí wọ́n fi máa ń sọ pé; “Kàí bi an kọlíjẹ̀bú Níbi an tọ̀nà Ìjẹ̀sàá bọ̀ Ọtáforíjọja ọ̀nà ni an kọlijẹ̀bú Ọmọ Egbùrùkòyàkẹ̀” Oríṣìíríṣìí oyè ni wọ́n máa ń jẹ ní Iléṣà tí wọn sì n jẹ ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà a rí Ògbóni ní Iléṣà bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Ara Ìwàrẹ̀fà mẹfà ni ògbóní méjèejì yí a ni Iléṣà ṣùgbọ́n ògbóni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ni aṣáájú àwọn ìwàrẹ̀fà náà. A rí àwọn olóyè bí Ọbaálá, Rísàwẹ́, Ọ̀dọlé, Léjòfi Sàlórò Àrápatẹ́ àti Ọbádò ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà bí wọ́n ti wà ni Iléṣà. Bákan náà, oríṣìíríṣìí àdúgbò ni a rí ti orúkọ wọn bá ara wọn mu ní àwọn ìlú méjèèjì yí fún apẹẹrẹ bí a ṣe rí Ọ̀gbọ́n Ìlọ́rọ̀ ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà náà ni a rí i ní Iléṣà, Òkèníṣà wà ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, Òkèṣà sì wà ní ìléṣà. Odò-Ẹsẹ̀ wà ní ìlú jèèjì yí bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹrẹ́jà pẹ́lù. Nínú gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, àdè tàbí ohùn ti Iléṣà àti ti Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló bá ara wọn mu jù lọ. Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló máa ń fi Ọwá tuntun han gbogbo Ìjẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bí olórí wọn tuntun lẹ́hìn tí ó bá ti ṣúre fún un tán. Tí ọ̀kan nínú wọn bá sì wàjà, ón ni ogún ti wọ́n máa ń jẹ lọ́dọ̀ ara wọn bí aya, ẹrú àti ẹrù. Ní ìgbà ayé ogun, ọ̀tún ogun, ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, wọ́n sì ní ọ̀nà tiwọn yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù. Nígbà tí ilẹ̀ Ilèṣà dàrú nígbà kan láyé ọjọ́ún, àrìmọ-kùnrin Ọwá àti àrìmọ-bìnrin Ọba Ìjẹ̀bù-Jẹ̀ṣà ni wọ́n fi ṣe ètùtù kí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó rójù ráyè, kí ó tó tùbà tùṣẹ. Nítorí pé Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò látàárọ̀ ọjọ́ wá, àjọṣe tiwọn tún lé igbá kan ju ti gbogbo àwọn ọbà ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó kù lọ nítorí pé “Ọwá àti Ògbóni Ìjẹ̀bù -Jẹ̀ṣà ló mọ ohun tí wọ́n jọ dì sẹ́rù ara wọn” Alaye sọ́kí lórí ìlú àti àwọn ènìyàn ìjẹ̀bù-jẹ̀ṣà Ìlù Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà jẹ́ ìlú kan pàtàkì ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà. Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yị́ ní Nàìjéríà. Apá ìwọ́ oòrùn ni ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà wà ní ilẹ̀ Yorùbá tàbí káàárọ́ - oò- jíire. Ìlú Ilẹ́ṣà ti ó jẹ́ olú ìlú fun gbogbo ilẹ̀ jẹ̀ṣà jẹ́ nnkan ibùsọ̀ mẹ́rìnléláàádọ́rin sí ìlú Ìbàdàn tí jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ìlú Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà sì tó nnkan bí ibùsọ̀ mẹ́fà sí Iléṣà ní apá àríwá ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà. Ní títóbi, ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni ó pọwọ́lé ìlú Iléṣà ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà, òun si ni olú ìlú fún ìjọba ìbílẹ̀ Obòkun ọ́un kí wọn tó tún un pín sí ọ̀nà mẹ́rin; síbẹ̀ náà òun ni olú ìlú fún ìjọba ìbìlẹ́ ààrin gùngùn obòkun. Àdúgbò márùnún pàtàkì ni wọ́n pín ìlú yìí sí kí bà lè rọrùn fún ètò ìjọ̀ba síṣe àti fúniṣẹ́ Ìlọ́rọ̀, Ọ̀kènísà àti Òdògo. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àdúgbò yí ló ní Olórí ọmọ tàbí lóógun kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ aṣáájú fún ọmọ àdúgbò rẹ̀ òun ní aṣáájú fún iṣẹ́kíṣẹ́ àti tí ó bá délẹ̀ láti ṣe ni àdúgbó, bẹ́ẹ̀ ni, ó sì tún jẹ́ aṣojú ọba fún àwọn ọmọ àdúgbò rẹ̀. Òdògo nìkan ni kò fi ara mọ́ èlò yí tó bẹ́ẹ̀ nítorí ìtàn tó bí i fi hàn pé ìlú ọ̀tọ̀ gédégédé ni òun. Àwọn ènìyàn ọ̀gbọ́n náà ń fẹ́ máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìgbà ìwásẹ̀ ti fi hàn wí pé wọn kò ní nnkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Lòde òní, nnkan ti ń yàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ nítorí pé àjọṣẹ tí ó péye ti ń wàyé láàárín ọ̀gbọ́n náà àti àwọn ọ̀gbọ́n yòókù. Ẹ̀rí tí ó fi hàn gbegbe pé àwọn Ìjẹ̀ṣà gba ìlù Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bi ìlú ti ó tẹ̀ lé Iléṣà ni ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni pé ìjókòó àwọn lọ́balọ́ba ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, Ọwá ìlẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà máa ń yàn àn lé. Síwájú sí i, nípa ti ìlànà oyè jíjẹ, ó ní iye ọjọ́ tí Ọwá tuntun gbọ́dọ̀ lò ní Ijẹ̀bù - Jẹ̀���à láyé ọjọ́un. Ọba Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà ni ó máa ń gbé Ọwá lésẹ̀ tí ó sì máa ń ṣúre fún un kí wọn tó gbà á gẹ́gẹ́ bí ọwá àti olóri gbogbo ọba ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà. Láti túnbọ̀ fi pàtàkì ìlú Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà hàn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú ìtàn ìwásẹ̀, ti Ọwá bá fẹ́ ṣe ìdájọ́ fún ọ̀daràn apànìyàn kan, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gbódọ̀ wà níjòkó, bí èyí kò bà rí bẹ́ẹ̀, Ọwá gbódọ̀ sùn irú igbẹ́jọ́ tábi ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ sí ọjọ́ iwájú. Ìdí nìyí tí wọ́n ṣe máa ń sọ pé “Ọwa ràà dáni í pa K Ìjẹ̀bu -Jẹ̀ṣà mọ mọ̀n Kọ́wá bá a pani Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà á gbọ́” Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ pàtàkì jùlọ tí àwọn ènìyàn ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ń ṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó jẹ́ àgbẹ̀ alárojẹ, bẹ́ẹ̀ ni a tún rí àwọn tó mú àgbẹ̀ àrojẹ mọ́ àgbẹ̀ agbinrúgbìn tó ń mówó wọlé lọ́dọ́ọdún àti láti ìgbàdégbà. Àwọn irúgbìn tí wọ́n ń gbìn fún àrojẹ ni, iṣu, ẹ̀gẹ́ (gbáàgúdá) ikókó, ìrẹsì, àgbàdo, kọfí, òwù àti obì sì jẹ́ àwọn irù-gbìn tó ń mówó wálé fún wọn. A rí àwọn oniṣẹ-ọwọ́ bíi, alágbẹ̀dẹ, onílù. agbẹ́gilére, àwọn mọlémọlé àti àwọn kanlékanlé. Àwọn obìnrin wọn náà a máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́-ọwọ́, lára wọn ni aró dídá, apẹ ati ìkòkò mímọ àti aṣọ híhun pẹ̀lú. Bákan náà, wọ́n tún jẹ́ oníṣowò gidi. Ọmọ ìyá ni ẹlẹ́dẹ̀ àti ìmọ̀dò, bẹ́ẹ̀ náà sì ni inàki àti ọ̀bọ, gbogbo ibi tí a bá ti dárúkọ Ìjẹ̀ṣà ni a á ti máa fi ojú oníṣòwo gidi wò wọ́n. Elèyìí ni a fi ń pè wọ́n ní “Òṣómàáló” nítorí kò sí ibi tí a kó ti lè rí Ìjẹ̀ṣà ti ọ̀rọ̀ ìṣòwò bá délẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí irúfẹ́ owo tí wọn kò lè ṣe, ohun tí ó kó wọn ni irìnra ni olé àti ọ̀lẹ. “Alápà má ṣiṣẹ́” ni àwọn Ìjẹ̀ṣà máa ń pe àwọn ti kò bá lè ṣiṣẹ́ gidi. Wọn ko sì fẹ́ràn irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ràrá. Ìjẹ̀ṣà kò kọ̀ láti kọ ọmọ wọn lọ́mọ tí ó bá jalè tàbí tí kò níṣẹ́ kan pàtàkì lọ́wọ́. Wọ̀n á sí máa fi ọmọ wọn tí ó bá jẹ́ akíkanjú tàbí alágbára yangàn láwùjọ. “Òkóbò nìkan ni kìí bímọ sí tòsí, a ní ọmọ òun wà ní òkè-òkun” Bákan náà ni pé “arúgbó nìkan ni ó lè parọ́ ti a kò lè já a nítorí pé àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ti kú tán” Purọ́ n níyì, ẹ̀tẹ́ ní ń mú wá, bi irọ́ ni, bí òótọ́ ni pé àwọn Ìjèṣà jẹ́ akíkanjú, ẹ wo jagunjagun Ògèdèngbé “Agbógungbórò” Ọ̀gbóni Agúnsóyè, “Ologun abèyìngọgọú, ó pẹ̀fọ̀n tán, ó wojú ìdó kọ̀rọ̀, Ọ̀dọ̀fin Arówóbùsóyè, Ọ̀gbọ́kọ̀ọ́ndọ̀ lérí odi kípàyẹ́ bì yẹ̀ẹ̀yẹ̀ẹ̀ séyìn” Ológun Arímọrọ̀ àti àwọn Olórúkọ ńláńlá ni ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà láyé ọjọ́un. Tí a bá tún wo àwọn oníṣòwò ńláńlá lóde òní nílẹ̀ Yorùbá jákèjádò, “Ọkan ni ṣànpọ̀nná kó láwùjọ èpè” ni ọ̀rọ̀ ti Ìjẹ̀ṣà. Nínú wọn ni a ti rí Àjànàkú, Erinmi lókun, Ọmọ́le Àmúùgbàngba bíu ẹkùn, S.B. Bákàrè Olóye méjì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo àti Onìbọnòjé àtàri àjànàkù tí kì í ṣẹrù ọmọdé. Mé loòó la ó kà lẹ́hín Adépèlé ni ọ̀rọ̀ wọn. Àwọn ọmọ Ìjèbú Jẹ̀ṣà jẹ́ aláfẹ́ púpọ̀ pàápàá nígbà tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀. Àwọn ènìyàn ti o fẹ́ràn àlàáfíà, ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀ láàárin onílé àti àlejò sì ni wọ́n pẹ̀lú. Wọn máa ń pín ara wọn sí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ láti ṣe iṣẹ́ ìlú láti jọ kẹ́gbẹ́ àjùmọ̀ṣe lẹ́nu iṣẹ́ àti oríṣìíríṣìí ayẹyẹ nílùú pẹ̀lú. “Àjèjé ọwọ́ kan kò gbẹ́rù dóri” àjùmọ̀ṣè wọn yìí mú ìlọsíwájú wá fún ìlú náà lọ́pọ̀lọ́pọ̀ “Abiyamọ kì í gbọ́ ẹkún ọmọ rẹ̀ kò má tatí were” ni ti àwọn ọmọ Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà sí ohunkóhun tí wọ́n bá gbọ́ nípa ìlú wọn. Bí ọ̀rọ̀ kan bá délẹ̀ nípa iṣẹ́ ìlú, wọn máa ń rúnpá-rúnsẹ̀ sí i, wọ́n á sì mú sòkòtò wọn wọ̀ láti yanjú irú ọ̀rọ̀ náà. Ọmọ ọkọ ni àwọn ọmọ ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ní tòótọ̀. Síwájú sí i, oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ó bá òde òní mu ni wọ́n ti là sí àárín ilú láìní ọwọ́ ìjọba kankan nínú fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ìlú wọn. Fún àpẹẹrẹ Ilé - Ẹ̀kọ́ gíga (Grammar Schoo) méji tí ó wà ní ilú náà, òógùn ojú wọn ni wọ́n fi kọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni Modern School wọn. Ọjà ilú, ilé-ìfìwé rànṣẹ́ àti gbàngàn ìlú ti o nà wọn tó àádọ́ta àbọ̀ ọ̀kẹ́ naira: Àwọn ọ̀nà títí tí wọ́n bójú mu tí wọ́n sì bá ti òde òní mu náà ni wọ́n ti fi òógùn ojú wọn là láìsí ìrànlọ́wọ́ ìjọba kankan. Adébáyọ̀ Fálétí, ògúná gbòngbò ti ó gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ jade láyé. Àwọn iwé ìròyìn gbe jade wi pé Adébáyọ̀ Fálétí, ògúná gbòngbò ninú àwọn ti ó gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ ni àgbáyé, re ibi àgbà nrè ni ọjọ́ ìsimi ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù keje, ọdún Ẹgbàálémẹ́tàdinlógún. Ọmọ ọdún mẹrindinlaadọrun ni olóògbé Fálétí ki wọn tó jade láyé. Ni ìgbá ayé olóògbé Adébáyọ̀ Fálétí, ó jẹ́ ìkan ninú àwọn òṣìṣẹ́ àkọ́kọ́ ni ilé iṣẹ́ amóhùn-máwòrán àkọ́kọ́ ni ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú ti wọn dá sílẹ̀ ni Ìbàdàn ti ó jẹ́ olú ilú ẹ̀yà Yorùbá ni ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀ èdè Nigeria. Ó gbé èdè Yorùbá lárugẹ nipa ṣi ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì si èdè Yorùbá, ó kọ ìwé itumọ̀ ọ̀rọ̀ nipa li lo orúkọ Yorùbá. Kò tán síbẹ, oníròyìn ni, ó fi eré ìtàgé gbé èdè Yorùbá lárugẹ nipa di dá ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Ọ̀yọ́ fún ìgbéga eré ìtàgé silẹ̀ ni ọdún mejidinlaadọrin sẹhin. Lára àwọn eré Yorùbá ti olóògbé Adébáyọ̀ Fálétí kọ, ti ó si ṣe ni “Mágùn, Àfọ̀njá, Baṣọ̀run Gáà àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ́ lọ. Ẹ̀kọ́ pọ̀ fún ọ̀dọ́ ayé òde òní lati kọ́ lára ìgbésí ayé olóògbé Adébáyọ̀ Fálétí. Lára ẹ̀kọ́ yi ni wi pe, ìwé kí kà ṣe pàtàkì, bi kò ti ẹ̀ si ìrànlọ́wọ́ lati ka ìwé ni ọmọdé, bi enia bá ka ìwé ni àgbà yio wúlò. Olóògbé Adébáyọ̀ Fálétí padà si ilé-ìwé lati lọ pari ìwé mẹfa ti ó dá dúró nigbati kó si agbára fún bàbá rẹ. Lẹhin eyi ó fi àgbà ara ka ìwé ni ilé-ìwé ẹ̀kọ́ giga. Ó gbé ìgbésí ayé rere nipa ìtọ́jú àwọn ọmọ àti ìyàwó, ó si fún àwọn ọmọ ni ẹ̀kọ́ ilé àti ti ilé-ìwé. Fún àwon iṣẹ́ ribiribi yi, olóògbé Adébáyọ̀ Fálétí gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn àpínfún ni orilẹ̀ èdè Nigeria àti ni òkè-òkun. Ẹ jẹ ki a gbé èdè àti àṣà Yorùbá Lárugẹ Ìpínlẹ̀ Èkó ṣe Àjọyọ̀ Ìdásílẹ̀ Àádọ́ta Ọdún Ìjọba-àpapọ̀ sọ Èkó di ìpínlẹ̀ ni àádọ́ta ọdún sẹhin. Èkó jẹ́ olú ilú fún gbogbo orilẹ̀ èdè Nigeria tẹ́lẹ̀ ki wọn tó gbe lọ si Abuja. Ìpínlẹ̀ Èkó jẹ ikan ninú ipinle mẹ́fà Yorùbá. Yorùbá ni “Èkó gba olè, ó gba ọlẹ”, ọ̀rọ̀ yi jẹ wi pé kò si irú ẹni ti ko si ni ìpínlẹ̀ Èkó nitori Èkó gba olówó, ó si gba aláini àti wi pé iṣẹ́ pọ̀ ni Èkó ju gbogbo ìpínlẹ̀ yoku lo. Kò si ẹ̀yà tàbi ẹ̀sìn Nigeria ti kò si ni Èkó. Nitori èyi èrò pọ̀ jù ilẹ̀ lọ nitori omi ló yi Èkó ká. Èkó ṣe àjọ̀dún lóri agbami – Lagos celebrate on the Ocean Àwọn Gómìnà ti ó ti jẹ lati ìgbà ti wọn ti dá ìpínlẹ̀ Èkó silẹ̀ ni wọnyi: Gómìnà Kini – Ọ̀gágun Àgbà Mobọ́lájí Johnson – Gómìnà fún ọdún mẹjọ – àádọ́ta ọdún si ọdún méjìlélógójì sẹhin Gómìnà Keji – Gómìnà Ori Omi Adékúnlé Lawal – Gómìnà fún ọdún méjilá – ọdún mejilélógójì titi di ogóji ọdún sẹhin Gómìnà Kẹta – Ọ̀gágun Ori Omi Ndubuisi Kanu – Gómìnà fún ọdún kan – ogójì ọdún titi di ọdún mọ́kàndinlógójì sẹhin Gómìnà kẹrin – Ọ̀gágun Ori Omi Ebitu Ukiwe – Gómìnà fún ọdún kan – ọdún mọ́kàndinlógóji titi di ọdún méjidinlógóji sẹhin Gómìnà Karun – Alhaji Lateef Jakande – Gómìnà Ìjọba Alágbádá fún ọdún mẹrin – lati ọdú́n mejidinlogoji titi di ọdún merinlelogbon sẹhin Gómìnà Kẹfà – Ọ̀gágun Òfúrufú – Gbọ́láhàn Múdàṣírù – Gómìnà fún ọdún meji – ọdú́n mẹ́tàlélogbon di ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n Gómìnà Keje – Ọ̀gá Adarioko Ojúomi Mike Akhigbe – Gómìnà fún ọdún meji – ọdú́n mọ́kànlélọ́gbọ̀n di ọdún mọ́kàndinlọ́gbọ̀n sẹhin Gómìnà Kẹjọ – Ọ̀gágun Àgbà Rájí Ràsákì – Gómìnà fún ọdún mẹrin – ọdú́n mọ́kàndinlọgbọn di ọdú́n márùndinlọ́gbọ́n sẹhin Gómìnà Kẹsan – Ọ̀gá Michael Ọ̀tẹ́dọlá – Gómìnà fún ọdún kan àti oṣù mẹwa – ọdú́n márùndinlọ́gbọ́n titi di ọdún mẹ́rinlélógún sẹhin Gómìnà Kẹwa – Ọ̀gágun Ọlágúnsóyè Oyinlọlá – Gómìnà fún ọdún meta – ọdún mẹ́rinlélógún di ọdún mọ́kànlélógún sẹhin Gómìnà Kọkànlá – Ọ̀gágun Mohammed Buba Marwa – Gómìnà fún ọdún mẹ́ta – ọdún mọ́kànlélógún di ọdún mejidinlógún sẹhin. Gómìnà Kejilá – Ọ̀gbẹ́ni Bọla Ahmed Tinubu – Gómìnà Ìjọba Alágbádá fún ọdún mẹjọ – ọdún mejidinlógún titi di ọdún mẹwa sẹhin Gómìnà Kẹtàlá – Ọ̀gbẹ́ni Babátúndé Rájí Fáṣọlá – Gómìnà Ìjọba Alágbádá fún ọdún mẹ́jọ – ọdún mẹwa titi di ọdún meji sẹhin Gómìnà Kẹrinlá – Ọ̀gbẹ́ni Akínwùnmí Ambọde – Gómìnà lọ́wọ́lọ́wọ́ lati ọdún meji titi di òni Yàtọ̀ si ìgbà Ìjọba Ológun, Èkó gbádùn ìdúróṣinṣin ni àsìkò Ìjọba Alágbádá tàbi Ìjọba Tiwantiwa lati ọdún kẹtàdínlógún sẹhin. Eyi jẹ ki ipinle Èkó mókè ju gbogbo ìpínlẹ̀ yókù lọ. Ìnáwó rẹpẹtẹ ni ìsìnkú arúgbó jẹ́ ni ilé Yorùbá. Bi arúgbó bá kú ni ilé Yorùbá ki ṣe òkú ọ̀fọ̀ ṣùgbọ́n òkú ijọ àti ji jẹ, mi mu ni pàtàki bi irú arúgbó bá bi àwọn ọmọ ti ó ti dàgbà. Gbogbo ẹbi, ará àti ilú yi ó parapọ̀ lati ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin fún irú arúgbó bẹ́ ẹ̀. Àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ yi o ṣe oriṣiriṣi ẹ̀yẹ ìbílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ lati gbé ìyá tàbi àgbà bàbá àgbà relé. Bi eléré ìbílẹ̀ kan ti nlọ ni òmíràn yio de, eleyi lo njẹ́ ki ilú kékeré dùn. A o ṣe àpẹrẹ àṣà ìsìnkú ìbílẹ̀ fún arúgbó pẹ̀lú ni Ìbòròpa Àkókó ilú Yorùbá ni ẹ̀gbẹ́ Ìkàrẹ́-Àkókó ti Ipinle Ondo, orile-ede Nigeria. Oríkì* jẹ ọ̀rọ̀ ìwúrí ti Yorùbá ma nlò lati fi sọ ìtàn àṣà àti ìṣe ìdílé lati ìran dé ìran. Ninú oríkì ni a ti lè mọ ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ẹbí ẹni àti ohun ti a mọ ìdílé mọ́, bí i irú iṣẹ ti wọn nṣe ni ìdílé, oriṣiriṣi èdè ìbílẹ̀ Yorùbá, oúnjẹ ti wọn njẹ àti èyí ti wọn ki i jẹ, ẹ̀sìn ìdílé, àdúgbò ti wọ́n tẹ̀dó si tàbi ìlú ti a ti ṣẹ̀ wá, àṣeyọrí ti wọn ti ṣe ni ìran ẹni àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ. Ni inú oríkì ti a ó bẹ̀rẹ̀ si i kọ, a ó ri àpẹrẹ ohun ti Yorùbá ṣe ma a nsọ oríkì pàtàki fún iwuri nigbati ọkùnrin, obinrin, ọmọdé àti ẹbí ẹni bá ṣe ohun rere bi ìṣílé, ìgbéyàwó, àṣeyorí ni ilé-iwé, oyè jijẹ tàbi ni ayé òde òni, àjọyọ̀ ọjọ́ ìbí. Oríkì jẹ ikan ninú àṣà Yorùbá ti ó ti nparẹ́, nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá bẹ̀rẹ̀ si kọ èdè àti àṣà wọn sílẹ̀ fún èdè Gẹ̀ẹ́sí. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ oríkì ti ìyá Olùkọ̀wé yi sọ fún ni ibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ ni ojú ìwé yi. A ó bẹ̀rẹ̀ si kọ oríkì oriṣiriṣi ìdílé Yorùbá. Ọmọ ẹlẹ́ja ò tú mù kẹkẹ Ọmọ a mẹ́ja yan ẹja Ọmọ ò sùn mẹ́gbẹ̀wá ti dọ̀ ara rẹ̀ Ọmọ gbàsè gbàsè kẹ́ ṣọbinrin lọyin Ọmọ kai, eó gbé si yàn ún Ọmọ a mú gbìrín eó b’ọ̀dìdẹ̀ Ìṣò mó bọ, òwíyé wàarè Ọmọ adáṣọ bù á lẹ̀ jẹ Ọmọ a má bẹ̀rẹ̀ gúnyán k’àdó gbèrìgbè mọ mọ̀ Ọmọ a yan eó meka run Ọmọ a mẹ́ kìka kàn yan ẹsinsun t’ọrẹ É e ṣojú un ríro, ìṣẹ̀dálẹ̀ rin ni Ọmọ a mi malu ṣ’ọdún ìgbàgbọ́ Ọmọ elési a gbàrùnbọ̀ morun Ọmọ elési a gbàdá mo yóko Èsì li sunkún ètìtù kọ gbà àrán bora li Gèsan Ọba Ọmọ Olígèsan òròrò bílẹ̀ Ọmọ alábùṣọrọ̀, a múṣu mọdi Àbùṣọrọ̀ lu lé uṣu, mọ́ m’ẹ́ùrà kàn kàn dé bẹ̀ Kare o ‘Lúàmi, ku ọdún oni o, è í ra ṣàṣe mọ ri a (Àṣẹ) Ni ìgbà àtijọ́, ọkùnrin kan wa ti orúkọ rẹ njẹ́ Ìgbéraga. Wọ́n bi Ìgbéraga si ilé olórogún, àwọn ìyàwó bàbá́ rẹ yoku ni ó tọ nitori ìyá rẹ kú nigbati ó wà ni kékeré. Lẹhin ti o tiraka lati pari iwé mẹ́fà, gẹ́gẹ́ bi ọ̀dọ́, ó gbéra lọ si ilú Èkó nibiti ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ Ẹlẹ́ja. Ó nṣe dáradára ni ibi iṣẹ́ ki ó tó gbọ́ ìròyìn ikú bàbá rẹ. Ìgbéraga pinu lati padà si ilú rẹ lati gba ogún ti ó tọ́ si lára oko kòkó rẹpẹtẹ ti bàbá rẹ fi silẹ̀. Ohun fúnra rẹ ra oko kún oko bàbá rẹ ti wọn pín fun. Ó di ẹni ti ó ri ṣe ju àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku. Eyi jẹ ki gbogbo àwọn ọbàkan rẹ gbójú le fún ìrànlọ́wọ́. Ni igbà ti ó yá, o ni ilé àti ọlà ju gbogbo àwọn yoku ni abúlé ṣùgbọ́n kò to, ó bẹ̀rẹ̀ si ra oko si titi dé oko àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku. Eyi jẹ́ ki ó sọ àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku di alágbàṣe ni oko ti wọn jogún. Inú àwọn ọmọ bàbá rẹ wọnyi kò dùn si wi pé wọn ti di atọrọjẹ àti alágbàṣe fún àbúrò wọn ninú ilé ara wọn. Yorùbá ni “Àṣejù Baba Àṣetẹ́”. Ìgbéraga bẹ̀rẹ̀ si ṣe àṣejù, kò dúró lati má a fi ọrọ̀ rẹ yangà si gbogbo ará ilú pàtàki si àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, ó jọ ara rẹ lójú, ó si nsọ ọ̀rọ̀ lai ronú tàbi gba ikilọ̀ àwọn àgbà ti wọn mọ ìbẹ̀rẹ̀ rẹ. Kò mọ̀ wi pé ohun ngbẹ́ ikòtò ìṣubú fún ara rẹ́. Ni ọjọ́ kan, ó pe ọ̀kan ninú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ti ó sọ di alágbàṣe ninú oko rẹ tẹ́lẹ̀ ó si bu, ó pe e ni aláìní dé ojú rẹ. Ẹ̀gbọ́n ké pẹ̀lú omijé lójú pé “Bi ó bá jẹ ìwọ ni Ọlọrun, ma ṣe iwà burúkú yi lọ, ṣùgbọ́n bi ó bá jẹ́ enia bi ti òhun, wà á ká ohun ti o gbin yi”. Ni àárọ̀ ọjọ́ kan, Ìgbéraga ji ṣùgbọ́n kò lè di de nitori ó ti yarọ. Wọ́n gbe kiri titi fún itọ́jú ṣùgbọ́n asán ló já si. Ìṣòro yi jẹ ki ó ta gbogbo ohun ini rẹ ti ó fi nyangàn titi o fi di atọrọjẹ. Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pe àṣejù ohunkóhun kò dára pàtàki ki enia gbójúlé ọrọ̀ ilé ayé bi ẹni pé àwọn ti ó kù kò mọ̀ ọ́ ṣe, nitori Yorùbá sọ wi pé “kìtà kìtà kò mọ́là, Ká ṣiṣẹ́ bi ẹrú kò da nkan, Ọlọrun ló ngbé ni ga”. Alágbàṣe ni oko Kòkó ti wọn jogún Ẹ ṣe àyẹ̀wò ìwé akéwì-orin ni èdè Yorùbá ti àwọn ọmọ ilé-ìwé n kọ́ sórí ni ilé-ìwé ilẹ̀ Yorùbá ni ayé àtijọ: Iṣẹ́ ni oògùn ìṣẹ́, múra si iṣẹ́ rẹ ọ̀rẹ́ mi, iṣẹ́ ni a fi i di ẹni gíga Bí a kò bá rẹ́ni fẹ̀hìn tì, bí ọ̀lẹ là á rí Bí a kò bá rẹ́ni gbẹ́kẹ̀lé, à á tẹra mọ iṣẹ́ ẹni Ìyá rẹ lè lówó lọ́wọ́, Bàbá si lè lẹ́ṣin leekan Bí o bá́ gbójú lé wọn, o tẹ́ tán ni mo sọ fún ọ Ohun ti a kò bá jìyà fún kì í lè tọ́jọ́ Ohun ti á fara ṣiṣẹ́ fún ní í pẹ́ lọ́wọ́ ẹni Apá lará, ìgunpá niyèkan Bí ayé n fẹ́ ọ loni, bí o bá lówó lọ́wọ́, ni wọn má a fẹ́ ọ lọla Tàbí tí o bá wà ní ipò àtàtà, ayé a yẹ́ ọ sí tẹ̀rín-tẹ̀rín Jẹ́ kí o di ẹni n rágó, kí o ri bí ayé ti n yínmú sí ọ Ẹ̀kọ́ sì tún n sọni dọ̀gá, mú́ra kí o kọ dáradára Bí o sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, tí wọn fi ẹ̀kọ́ ṣe ẹ̀rín rín Dákun má ṣe fara wé wọn Ìyà n bọ̀ fọ́mọ tí kò gbọ́n, ẹkún n bẹ fọ́mọ tó n sá kiri Má fòwúrọ̀ ṣeré, ọ̀rẹ́ mi, múra sí iṣẹ́ ọjọ́ n lọ Ẹ kú àsikò yi o. Bawo ni ipalẹ̀mọ́ ọdún Kérésìmesì àti ọdún titun? Ni àsikò ọdún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ma nfi oúnjẹ àjẹ jù àti ọti à mu para yọ ayọ̀ ọdún. Ni òtitọ́, ará ilú nké pé kò si owó àti ọ̀wọ́n ọjà, nitori eyi ayé àjẹ jù le ma si, ṣùgbọ́n bi ẹlòmíràn kò ni owó, á gba àwin ọti pé àwọn fẹ́ fi pa irònú rẹ́. Àwọn miran nlo egbò igi olóró ti á gbọ́ wi pé ó ti wọ́pọ̀ ni orilẹ̀ èdè Nigeria pàtàki laarin àwọn ọ̀dọ́. À fọwọ́ fà ni gbogbo eyi. Kò si iyàtọ̀ laarin ọlọ́tí pẹ̀lú ẹni ti ó mu egbò igi olóró àti wèrè, nitori ihùwà ọlọ́ti àti ẹni lo oògùn olóró kò yàtọ̀ si ti wèrè bi wọn bá ti yó. Bi ẹni ti ó mu àmu para àti ẹni lo egbò igi olóró bá wa ọkọ̀, àkóbá ni fún àwọn awakọ̀ yoku àti àwọn arin nà yoku. Ki ọdún titun lè bá wa láyọ̀, ikilọ ni àsikò yi ni wi pé “Ki ẹni bá mú ọti tàbi ẹni tó lo egbò igi olóró ma ṣe wa ọkọ̀”. Ẹ kú ipalẹ̀mọ́ ọdún o. Bi ọdún bá sún mọ́ etílé, oúnjẹ àti ohun èlò gbogbo maa nwọn nitori àwọn ọlọ́jà yio ti fi owó kún ọjà nitori èrò ti ó fẹ́ ra ọjà maa n pọ̀ si ni àsikò yi. Pa pọ̀ mọ́ ipari ọdún ni àwọn ti ó fi ayẹyẹ iyàwó, òkú, ọdún Kérésìmesì àti ṣíṣe miràn si àsikò yi. Kò si ẹni ti kò ni nkankan. Pé èniyàn ni ara li le tàbi ó lè jẹun, ó tó nkan. Ilẹ̀ Yorùbá ni ohun ọrọ̀ ajé àti oúnjẹ ni oriṣiriṣi tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lati igbà ti Ìjọba àpapọ̀ ti da gbogbo ẹ̀yà orilẹ̀ èdè Nigeria pọ̀ ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si pin owó epo rọ̀bì ni ìfẹ́ oúnjẹ àti ọjà òkèèrè/òkè-òkun ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di ọ̀lẹ àti ẹni ti kò ni ìrònú. Àsikò tó lati ṣe àyípadà, ki a jẹ ohun ti a ba gbin ni ilẹ̀ wa, nitori owó epo rọ̀bì ti gbogbo ilú gbójúlé ti fidi janlẹ̀. Ki owó epo rọ̀bì tó dé, a nfi ìrẹsì ṣe ọdún pàtàki fún àwọn ọmọdé, ṣùgbọ́n iresi ti wọn gbin ni ilẹ̀ wa ni a njẹ. Bi a ra oúnjẹ ilẹ̀ wa dipò oúnjẹ òkè-òkun, àgbẹ̀ yi o ri owó, a o si mọ irú oúnjẹ ti a njẹ ju ìrẹsì oníke ti wọn nkó wọ ilú. Ki ṣe dandan ni ki a se ìrẹsì fún ọdún, a lè fi oúnjẹ ẹ̀yà miràn ṣe ọdún fún àwọn ọmọ. Fún àpẹrẹ, Ìjẹ̀bú lè se ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ rirò àti iyán dipò ìkọ́kọrẹ́ fún ọdún tàbi ki Èkìtì se ìkọ́kọrẹ́ fún ọdún dipò iyán àti ẹ̀fọ́ rirò àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ. Ẹ jẹ́ ki a gbé oúnjẹ ilẹ̀ wa lárugẹ. Èsi ibò ti wọn di ni ilú Amẹ́rikà ni oṣù kọkànlá, ọjọ́ kẹjọ jade ni òru ọjọ́ kẹjọ mọ́jú ọjọ́ kẹsan ọdún Ẹgbàálémẹ́rindinlógún. Àwọn mẹta ti ó gbé àpóti ibò fún ipò olóri òṣèlú ni, Hillary Clinton, obinrin àkọ́kọ́ lati dé irú ipò bẹ́ ẹ̀ fún ẹgbẹ́ (Democrat), Donald J. Trump, Oniṣòwò nlá ti kò ṣe iṣẹ́ Ìjọba kankan ri fún ẹgbẹ́ (Republican) àti Gary Johnson fún ẹgbẹ́ kẹta (Libertarian). Èsi ibò yi ya gbogbo àgbáyé lẹ́nu nitori àwọn ọ̀rọ̀ ti Donald Trump (Olóri ẹgbẹ́ GOP) ti sọ siwájú nigbati ti ó polongo lati dé ipò. Àwọn ọ̀rọ̀ iko rira wọnyi lòdi si àwọn obinrin, ẹ̀yà miran ti ó yàtọ̀ si ẹ̀yà rẹ, àlejò, ẹlẹ́sin Mùsùlùmi àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ. Owe Yoruba so wipe “Bi Ẹlẹ́bọ kò bá peni, Àṣefín kò yẹni”. Donald Trump ò ka gbogbo ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú si nkankan tàbi dárúkọ Nigeria. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rò wi pé nitori Amẹ́rikà ti nṣe Òṣèlú ti wa ntiwa fún igbalélógòji ọdún, ẹni ti wọn yio yan si irú ipò yi á ni iwà àkójọ àti ẹ̀mi àkóso si onírúurú àwọn enia ti ó wà ni gbogbo àgbáyé. Òwe Yorùbá ni “Bi èniyàn bá ni kò si irú òhun, àwọn ọlọ́gbọ́n a máa wòye”. Lati igbà ti iròyin ibo ti jade pé Donald J. Trump ló wọlé, gẹ́gẹ́ bi wọn ti nṣe é, àwọn Olóri ilú àgbáyé ló kọ iwé tàbi pè lati ki ku ori ire. Ó ṣe ni laanu wi pé, àwọn tó wà ni ilé aṣòfin Nigeria, àti oriṣiriṣi àwọn Òṣèlú kékeré yókù lo nkọ iwé. Gbogbo ìròyìn lati Nigeria kò ri ọ̀rọ̀ àti ìṣò̀ro ti ó dojú kọ ilú ti wọn sọ mọ, ju ọ̀rọ̀ èsi ibò ni Amẹ́rikà. Eyi kò fi ọgbọ́n han nitori ìyà ti ó njẹ ará ilú Nigeria kọjá ki wọn ma sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Olóri Òṣèlú Nigeria, Muhammadu Buhari lati ṣe àyipadà kúrò ni iwà ibàjẹ́ ti ó ba ilú jẹ, ki ilú lè tòrò, ki ó si lè pèsè oúnjẹ àti ohun amáyédẹrùn fún ará ilú. Ìtàn fi yé wa wi pé Yorùbá ka ọ̀rọ̀ obinrin si ni àṣà Yorùbá bi ó ti ẹ jẹ wi pé obinrin ki jẹ Ọba nitori ni àṣà ilú, ọkunrin ló njẹ olóri. Obinrin kò pọ̀ ni ipò agbára. Àwọn ipò obinrin ni ‘Ìyáálé’, eyi jẹ́ iyàwó àgbà tàbi iyàwó àkọ́fẹ́ ninú ẹbí, pàtàki ni ilé o ni iyàwó púpọ̀ ṣùgbọ́n ọkùnrin ni ‘olóri ẹbí’. Ipò obinrin kò pin si idi àdìrò àti inú ilé yókù gẹ́gẹ́ bi Olóri Òṣèlú Nigeria, Muhammadu Buhari ti sọ. Obinrin Yorùbá ti ni àyè lati ṣe iṣẹ́ ti pẹ́, bi ó ti ẹ̀ jẹ́ wi pé àwọn iṣẹ́ obinrin bi oúnjẹ ṣí ṣe, ẹní hí hun, aṣọ hí hun, aró ṣi ṣe, òwú gbi gbọ̀n, ọjà ti tà (ẹ̀kọ́ ọrọ̀ ajé díẹ̀), oúnjẹ sí sè àti itọ́jú ẹbi ni obinrin nṣe. Àwọn ọkùnrin nṣe iṣẹ́ agbára bi iṣẹ́ ọdẹ, alágbẹ̀dẹ, àgbẹ̀ tàbi iṣẹ́ oko (iṣẹ́ fún ji jẹ àti mimu ẹbí). Obinrin ni ògúná gbongbo ni oníṣòwò òkèèrè, eyi jẹ ki obinrin lè ni ọrọ̀ àti lati lè gba oyè ‘Ìyálóde’. Fún àpẹrẹ, àwọn Ìyálóde ni ó njẹ Olóri ọjà ni gbogo ilẹ̀ Yorùbá àti alá-bójútó fún ọ̀rọ̀ obinrin. Gẹ́gẹ́ bi àṣà ibilẹ̀ Yorùbá, àwọn ọkùnrin gbà ki iyàwó wọn ṣe iṣẹ́ lati ran ẹbí lọ́wọ́, eyi lè jẹ́ nitori àwọn ọkùnrin ni iyàwó púpọ̀, nitori èyi, kò nira bi iyàwó kan tàbi méji bá lọ ṣòwò ni òkèèrè, àwọn iyàwó yókù yio bójú tó ilé. Àṣà òkè-òkun fi fẹ́ iyàwó kan àti ẹ̀sìn òkèère ti Yorùbá gbà ló sọ àdìrò di ipò fún obinrin àti “Alá-bọ́dó, Ìyàwóilé tàbi Oníṣẹ́-ilé” ti ó di iṣẹ́ obinrin. Obinrin ayé òde òní kàwé, ṣùgbọ́n bi wọn kò ti ẹ kàwé, gbogbo ẹni ti ó bá ni làákàyè fún àṣà, kò gbọdọ̀ já obinrin si ipò kankan ni ilé nitori obinrin ló ni gbogbo ilé. Ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ keje, oṣù kẹwa ọdún Ẹgbàálémẹ̀rindinlógún, ìròyìn pé àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ já lu ilé àwọn Adájọ́ ti wọn fi ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ kàn jade lẹhin ti wọn ti dúró titi ki “Ẹgbẹ́ Adájọ́” gbé àwọn iwé ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ yẹ̀wò . Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ròyìn pé wọn bá owó rẹpẹtẹ, pàtàki oriṣiriṣi owó òkè òkun, ni ilé awon Adájọ́ wọnyi. Lati igbà ti iroyin ti jade, àwọn ‘Ẹgbẹ́ Agbẹjọ́rò’ lérí pé àwọn yio da iṣẹ́ silẹ̀ ti Olóri Òṣèlú Muhammadu Buhari kò bá pàṣẹ ki wọn tú àwọn Adájọ́ naa silẹ̀ ni wéréwéré. Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, Adájọ́ àti Agbẹjọ́rò ki i ṣe iṣẹ́ nitori àgbà ni ó ndá ẹjọ́ bi ijà bá bẹ́ silẹ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá. Fun àpẹrẹ, bi àwọn ọmọdé bá njá, àgbàlagbà ti ó bá wà ni ilé ni yio là wọ́n, bi àwọn iyàwó-ilé bá njà, olóri ẹbi tàbi Àrẹ̀mọ ni yio la ijà. Bi ó bá jẹ́ ijà nitori ilẹ̀ oko, Baálẹ̀ Abúlé naa ni wọn yio kó ẹjọ́ lọ bá fún idájọ́, ti ó bá jẹ àdúgbò kan si ekeji ló njà, wọn á kó ẹjọ́ lọ bá Ọba ilú àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ. Lati wa idi òtitọ́, wọn lè kó àwọn ti ó njà lọ si ojúbọ Òriṣà lati búra. Lẹhin ti àwọn Ìlú-Ọba pin àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilú àwọn Aláwọ̀dúdú, iṣẹ́ Agbẹjọ́rò di ki kọ́ ni ilé-iwé giga. Kò si ọmọ Nigeria rere ti kò mọ̀ wi pé, ‘’Ẹ̀ṣẹ̀ nlá ijiyà kékeré tàbi ki ó má si ijiyà rara fún Olówó, ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kékeré ijiyà nla ni fún tálákà tàbi aláìní’’, nitori iwà burúkú àwọn Adájọ́ ti ó ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Agbejoro. A ri gbọ́ wi pé bi “Ọ̀gá Àgbà Agbẹjọ́rò” bá ni ẹjọ́ ni iwájú Adájọ́ lẹhin ti ẹjọ́ agbejoro ti dé iwájú Adájọ́, wọn yio kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ ti “Ọ̀gá Àgbà Agbẹjọ́rò” gbé wá. Eleyi jẹ́ ikan ninú idi pàtàki ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Agbejoro ti fẹ́ fi ọ̀nàkọnà dé ipò “Ọ̀gá Àgbà Agbẹjọ́rò”. Ó yẹ ki wọn gbé eyi yẹ̀wò nitori ni ilú ti òfin bá wà, kò yẹ ki ẹnikẹni kọjá òfin. Ni Òkè-Òkun, Gó́́mìnà, àgbà Òṣèlú àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ kò kọjá òfin. “Ẹni ma a bèrè ẹ̀tó lábẹ́ òfin yio lọ pẹ̀lú ọwọ́ mímọ́”, ẹ gb́e ọ̀rọ̀ yi yẹ̀wò bóyá bi wọ́n bá fi ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ kan Adájọ́, kò yẹ ki Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ wa idi. Ohun ti wọ́n bá fi ogún ọdún tàbi ju bẹ́ ẹ̀ lọ kọ́, ṣe é bàjẹ́ ni iṣéjú akàn, ṣùgbọ́n lati ṣe àtúnṣe lè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún bakan na a. Ó ṣe pataki ki gbogbo ọmọ ilú pinu ni ikan kan lati ṣe àtúnṣe lati bọ́ lọ́wọ́ ìnira ti ó wà ni ilú lọ́wọ́lọ́wọ́. Àyípadà tàbi Àtúnṣe yẹ ki ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òṣiṣẹ́ Ìjọba, àwọn ti ó nta ọjà, ọ̀gá ilé-iwé àti àwọn ọmọ ilé-iwé, àwọn òṣiṣẹ́ ilé-ìwòsàn, ọmọdé àti àgbà ilú. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà àti àwọn iwà ibàjẹ́ ti ó ti gbilẹ̀ fún ọdún pi pẹ́ ti ba nkan jẹ ni orilẹ̀ èdè Nigeria. Di ẹ ninú àwọn iwà burúkú wọnyi ni ki òṣiṣẹ́ ìjọba ji ẹrù àti owó Ìjọba fún ara wọn tàbi sọ ara wọn di alágbàtà ti o nsọ ọjà di ọ̀wọ́n nipa gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ. Eleyi lo njẹ ki àwọn iṣẹ́ ti ìjọba bá gbé sita lati tú ọ̀nà ṣe, lati pèsè iná mọ̀nàmọ́ná, omi àti ohun amáyédẹrùn miran wọn ju ti gbogbo àgbáyé lọ. Nitori òṣiṣẹ́ Ìjọba ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ti ó gba iṣẹ́ lè ma ṣe iṣẹ́ tàbi ki wọn ṣe iṣẹ́ ti kò dára. Ẹni ti ó nta ọjà á sọ̀rọ̀ si onibárà pẹ̀lú ẹ̀gàn, ojúkòkòrò, ìfẹ́ owó ki kó jọ ni ọ̀nà ẹ̀rú àti à ṣe hàn ló nfa iwà ibàjẹ́ àti olè jijà laarin àwọn Òṣèlú, olóri ẹ̀sìn, òṣiṣẹ́ Ìjọba, ọlọ́jà ti ó nkó ọjà pamọ́ lati fa ọ̀wọ́n, Olùkọ́ ilé iwé, ọmọ ilé-iwé kò ni itẹriba fún Olùko mọ́, àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ. Ki àyipadà rere lè dé bá ilú, ó yẹ ki onikálukú yẹ ara rẹ̀ wò fún àtúnṣe kúrò ninú àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà, iwà ibàjẹ́, ai ṣojú ṣe ẹni ninú ẹbi, ai bẹ̀rù àgbà, ji ja ilú lólè, ki kó owó ilú lọ si òkèèrè, ki kọ oúnjẹ ilú ẹni silẹ̀ fún oúnjẹ òkèèrè, ayẹyẹ àṣejù, ni ná owó ti èniyàn kò gbà àti ai ni ìtẹ́lọ́rùn. Ìpolongo tó nlọ lọ́wọ́ ni orilẹ́ èdè Nigeria ni pé “Àyípadà tàbi Àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi”. Yorúbà sọ wi pé “Igi kan ki da a ṣe igbó”, eyi túmọ̀ si wi pé ki i ṣe Olóri Ìjọba Òṣèlú àti àwọn Òṣèlú yoku nikan ni ó yẹ ki ó ṣe àtúnṣe ohun ti ó ti bàjẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣùgbọ́n gbogbo ọwọ́ ló yẹ ki ó ṣe àtúnṣe lati gbógun ti iwà ibàjẹ́. Ìjọba Ológun àkọ́kọ́ ni abẹ́ Olóògbé Ọ̀gágun Aguiyi Ironsi, da gbogbo ipinlẹ̀ pọ si abẹ́ Ìjọba àpapọ̀. Ki wọ́n tó dá àwọn ipinlẹ̀ pọ̀, àwọn ipinlẹ̀ ndàgbà sókè gẹ́gẹ́ bi ohun ti ó ṣe kókó fún wọn. Ipinlẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn, ti ẹ̀yà Yorùbá ngbé, ni ìgbéga ni abẹ́ Olóri Òṣèlú Ipinlẹ̀, Olóògbé́ Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àti ẹgbẹ́ Òṣèlú rẹ. Wọ́n pèsè ohun amáyédẹrùn igbàlódé bi ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé-iwé ọ̀fẹ́, ọ̀nà gidi, omi mi mun, iná mọ̀nàmọ́ná àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ ni gbogbo agbègbè ilẹ́ Yorùbá. Eleyi jẹ ki Yorùbá ri ohun mu yangàn. Yàtọ̀ si Ìjọba Ológun lábẹ́ Ọ̀gágun Yakubu Gowon, ti ó lo ọ̀pọ̀ owó epo rọ̀bì dáradára lati pèsè ohun amáyédẹrùn ti igbàlódé ti ilú ngbádùn titi di ọjọ́ oni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ìjọba Nigeria yókù ti ó ré kọjá lábẹ́ Ológun àti Òṣèlú kùnà nipa ipèsè ohun amáyédẹrùn fún orilẹ̀ èdè nitori iwà ibàjẹ́. Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ ti ó sọ wi pé “Ni ilú afọ́jú, olójú kan lọba”, laarin Ìjọba àpapọ̀, nitori iwà-ibàjẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, a lè sọ wi pé àwọn ipinlẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn, Èkìtì, Èkó, Ògùn, Ondó, Ọ̀ṣun àti Ọ̀yọ́ ṣe dáradára nipa ipèsè ohun amáyédẹrùn. Àmọ́, ‘ilọsiwájú’ yi kò tó nkankan lára ogún ti Olóògbé Olóyè Awólọ́wọ̀ ṣe silẹ̀. Kò si ipèsè ohun amáyédẹrùn pàtàki omi mi mun ni àwọn agbègbè tuntun lai yọ àdúgbò ọlọ́rọ̀ silẹ̀. Eleyi ló sọ gbi gbẹ́ ihò fún omi àti kànga lati wá omi fún mi mun di àṣà. Àwọn ipinlẹ̀ Yorùbá́ ti gbádùn ohun amáyédẹrùn igbàlódé fún ọjọ́ ti pẹ́, nitori èyi ni a ṣe mbẹ̀ àwọn Gómìnà ipinlẹ̀ Yorùbá pé ki wọn pèsè ‘’omi mi mun’ fún ará ilú gẹ́gẹ́ bi ẹ̀tọ́ lati dá àṣà gbi gbẹ́ ilẹ̀ bi ti Òkété lati wa omi ti kò ṣe e mu ni ọ̀pọ̀ igbà. Nitotọ àti ṣe ẹ̀yà orí tẹlẹ ṣugbọn a lérò wípé orúkọ gbogbo ẹ̀yà ara lati orí dé ẹsẹ á wúlò fún kíkà. Yorùbá fẹ́ràn àlejò púpọ̀. Ìwà ti ọmọ ilú lè hù ti yio fa ibinú, bi àlejò bá hu irú ìwà bẹ́ ẹ̀, wọn yio ni àlejò ni, ki wọn fori ji i. Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé “Ojú àlejò ni a ti njẹ igbèsè, ẹhin rẹ la nsaán”. Eyi fi hàn bi Yorùbá ti fẹ́ràn lati ma ṣe àlejò tó. Ìbàdàn ni olú-ilú ipinlẹ̀ Yorùbá ni Ìwọ̀-Oorun Nigeria tẹ́lẹ̀ ki Ìjọba Ológun ti Aguiyi Ironsi ti jẹ Olóri tó kó gbogbo ipinlẹ̀ Nigeria pọ si aarin lẹhin ti wọn fi ibọn gba Ìjọba lọ́wọ́ Òṣèlú ni aadọta ọdún sẹhin. Lẹhin oṣù keje ni aadọta ọdún sẹhin, àwọn Ológun fi ibọn gba Ìjọba ni igbà keji. Ti àkọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ nigbati wọn fi ibọn lé àwọn Òṣèlú àkọ́kọ́ lẹhin òmìnira kúrò ni ọjọ́ karùndinlógún, oṣù kini ọdún Ẹdẹgbaalemẹrindinlaadọrin. Lẹhin oṣù meje, àwọn Ológun tún fi ibọn gbà Ìjọba lọ́wọ́ àwọn Ológun ti wọn fi ibọn gbé wọlé ti Aguiyi Ironsi jẹ olóri rẹ. Lára Ìjọba Ológun àkọ́kọ ti Ọ̀gágun Aguiyi Ironsi ti jẹ́ Olóri Ìjọba ni wọn ti fi Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi jẹ Olóri ni ipinlẹ̀ Yorùbá dipò Òṣèlú Ládòkè Akintọ́lá ti àwọn Ológun pa. Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi gba Olóri-ogun Aguiyi Ironsi ni àlejò ni ibùgbé Ìjọba ni Ìbàdàn nigbati àwọn Ológun dé lati fi ibọn gba Ìjọba ni igbà keji. Nigbati àwọn Ajagun dé lati gbé Olóri Ogun Aguiyi Ironsi lọ, gẹ́gẹ́ bi àṣà Yorùbá, Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi bẹ̀bẹ̀ ki wọn fi àlejò òhun silẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kọ. Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi fi ara rẹ ji pé ti wọn ba ma a gbee, ki wọn gbé òhun pẹ̀lú. Nitori eyi àwọn Ológun gbe pẹ̀lú àlejò rẹ wọn si pa wọ́n pọ ni Ìbàdàn. Ni ọjọ́ kọkandinlọgbọn oṣù keje ọdún Ẹgbàálémẹ́rindinlógún, ilú péjọ pẹ̀lú ẹbi àti ará ni Adó-Èkìtì lati ṣe iranti Olóògbé Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi fún iranti iwà iṣòótọ ti ó hù titi dé ojú ikú pẹ̀lú àlejò àti ọ̀gá rẹ Olóri Ogun Aguiyi Ironsi ni aadọta ọdún sẹhin. Ikú àwọn ọkùnrin Aláwọ̀-dúdú ni ọwọ́ Ọlọpa ni orilẹ̀ èdè Àméríkà pọ̀ ju pi pa àwọn aláwọ̀ funfun tàbi laarin àwọn ẹ̀yà kékeré miran. Ọ̀sẹ̀ kini oṣù keje ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún ṣòro fún àwọn Àméríkà. Ìròyìn bi Ọlọpa funfun ti yin ibọn si ọkùnrin Aláwọ̀-dúdú ni ojú ọmọ àti aya nlọ lọ́wọ́ nigbati ìròyìn bi Ọlọpa funfun ti pa okunrin Aláwọ̀-dúdú miran bi ẹni pa ẹran ti tún jáde. Àwọn iroyin yi bi àwọn èrò ninú, nitori èyi, aláwọ̀ dúdú àti funfun tú jáde lati fi ẹ̀dùn hàn pé “Ìgbésí Ayé Aláwọ̀-dúdú ṣe pàtàki” pé àwọ lè yàtọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ kò yàtọ̀. Ó ṣe ni laanu pé Micah Johnson ọkùnrin Aláwọ̀-dúdú, jagunjagun fun orile ede Àméríkà, ló pa Ọlọpa marun, ó si ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ léṣe nipa gbi gbé òfin si ọwọ́ ara rẹ pẹ̀lú ibinu. Ìwà burúkú ti di ẹ̀ ninú àwọn Ọlọpa funfun yi hu ki ṣe ìwà ti ó wọ́pọ̀ laarin ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọlọpa aláwọ̀ funfun tàbi gbogbo Ọlọpa ti wọn nṣe iṣẹ́ ribiribi lati dá àbò bo àwọn ará ilú. Ó ṣe ni laanu pé àwọn Aláwọ̀-dúdú ni Ọlọpa nda dúró jù ni ojú ọ̀nà ọkọ̀, ti ó dẹ̀ n kú ni irú idá dúró bẹ́ ẹ̀. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, onidajọ ọ̀daràn kò ṣe idájọ òdodo fún Aláwọ̀-dúdú, èyi kò ran nkan lọ́wọ́. A lérò wi pé àwọn oníwà ìbàjẹ́ ti ó jẹ́ Olóri Òṣèlú ilẹ̀ Alawo dudu ti ó n ja ilú lólè lati kó irú, ọrọ̀ ilú lọ pamọ́ si àwọn ilú ti o ti dàgbà sókè yio ronú pìwàdà. Èrò ti ó n kú ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú nitori ọ̀nà ti kò dára, a i si ilé-ìwòsàn gidi, a i ni ohun amáyédẹrùn bi omi, iná mọ̀nàmọ́ná kò jẹ ki Aláwọ̀-dúdú Àméríkà lè fi orisun wọn yangàn. Ni Ìlú-Ọba, lẹhin ọdún mẹtalelogoji, èrò jade lati di ìbò bẹni-bẹ́ẹ̀kọ́ lori àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ Ìlú-Oyinbo méjidinlọ́gbọ̀n ni Ọjọ́bọ̀, oṣu Kẹfa, ọdún Egbàálémẹẹdógún. Idibò na a lọ wẹ́rẹ́ lai si ìjà, kò gbà ju ìṣéjú kan si meji lọ lati wọlé dibò ti ó bẹ̀rẹ̀ ni agogo meje àárọ̀ titi di aago mẹwa alẹ́. Lẹhin idibò, ni òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ keji idibò, ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ kẹrinlélógún, oṣù kẹfa, èsi ibò jade pé ibò bẹ́ẹ̀kọ́ ju ibò bẹni lọ, eyi ti ó túmọ̀ si wi pé, ará ilú ti ó fẹ́ ki wọn ‘kúrò’ ni ẹgbẹ́ Ilú-Oyinbo pọ̀ ju àwọn ti wọn ó fẹ́ ki wọn ‘dúró‘ ninú ẹgbẹ́. Bi èsì ibò ti jade, Olóri Òṣèlú Ilú-Ọba, David Cameron, jade lati bá ará ilú sọ̀rọ̀. Ninú ọ̀rọ̀ rẹ, ó ni nitori ohun polongo ki wọn dúró ninú ẹgbẹ́ Ilú-Oyinbo ṣùgbọ́n àwọn aráilú ti sọ̀rọ̀ wi pé ki wọn kúrò, nitori eyi ohun yio gbé Ijọba silẹ̀. Ẹ̀kọ́ fún Ìjọba tiwa ntiwa ni orilẹ̀ èdè Nigeria ni wi pé iwá ibàjẹ́ ti àwọn Òṣèlú nhu ni Àbùjá lai fi eti si ará ilú pé àwọn ẹ̀yà mẹ́yà orilẹ̀ èdè Nigeria fẹ́ dá Ìjọba wọn ṣe ju ki Òṣèlú joko si Àbùjá lati maa na owó gbogbo ará ilú. Ó yẹ ki wọn ronú bi wọn yio ti ṣe Ìjọba ti yio mu irọ̀rùn ba gbogbo ipinlẹ Nigeria. Ki wọn fi eti si ohun ti ará ilú lati Guusu dé Àriwá sọ, pé ki wọn joko sọ̀rọ̀ bi wọn yio ti ma bára gbé. Igbe àwọn Igbo ti pọ si lẹhin ti wọn jagun abẹ́lé, àwọn ẹya miran bi Yorùbá nkun ni abẹ́lẹ̀ pé àwọn ma fẹ dá dúró ki wọn san iṣákọ́lẹ̀ fún Ìjọba àpapọ̀. Ó yẹ ki Òṣèlú Nigeria ṣe àyẹ̀wò òfin ti aṣojú Ilú Ọba – Lugard fi da Guusu àti Àríwá pọ fún irọ̀rùn ìṣàkóso orilẹ̀ èdè Nigeria ni ọgọrunlemeji ọdún sẹhin. Nigeria gba Òmìnira ni bi ọdún mẹrindinlọgọta sẹhin. Lẹhin Òmìnira, àwọn Òṣèlú pàtàki ni Ìwọ̀-oòrùn lábẹ́ Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ fi ipò Òṣèlú ṣe iṣẹ́ ribiribi lati jẹ́ ki àwọn ará ilú jẹ èrè Òmìnira, ṣùgbọ́n lati igbà ti Ìjọba Ológun ti ó fi ibọn gba Ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ si ṣe Òṣèlú ni ilú ti bàjẹ́ si, wọn si rò wi pé àwọn lé fi ipá kó orilẹ̀ èdè pọ. Lati ọjọ́ ti aláyé ti dá ayé ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ti wà. Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú kún fún ọrọ̀ oriṣiriṣi, ṣùgbọ́n, iwà àpà, ojúkòkòrò, ki kó ti ilé dà si ita, àti ìfẹ́ àjòjì ju ara ilé ẹni lọ, ló fa iṣẹ́ ti ó pọ̀ ni Ilẹ̀-Aláwọ̀dúdú. Iwà burúkú wọnyi, pàtàki laarin àwọn Olóri ilú tàbi alágbára ló fa ti ta ara ẹni lẹ́rú si Òkè-Òkun, ogun abẹ́lé àti òwò ẹrú ti ayé òde òni ṣi wà. Àwọn Òṣèlú àti Olóri ilú kò ti kọ́ ọgbọ́n, nitori wọn nṣe àṣiṣe si nipa li lo iṣẹ ti wọn gbà lai ṣe kó owó ilú jẹ, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti iwà ibàjẹ́ ló fa ibàjẹ́ ohun amáyédẹrùn àti ìṣẹ́ laarin ọrọ̀ ni orilẹ̀ èdè Nigeria. Melo ninú ọmọ ayé òde òni ló ránti àwọn Ọlọ́rọ̀ ilẹ̀ Yorùbá ni aadọta ọdún sẹhin? Òmíràn kò mọ itumọ̀ ọ̀rọ̀ Èkó/Yorùbá pé “Bi ó ti ẹ lówó bi Da Rocha” lai bèrè pé tani Da Rocha? Àwọn Ọlọ́rọ̀ àná bi Candido Joao Da Rocha, Ọlọ́rọ̀ owó ọ̀kẹ́ aimoye àkọ́kọ́ ni orilẹ̀ èdè Nigeria ti ilú Èkó, Olóyè Adéọlá Odùtọ́lá ọ̀gá Oníṣòwò ti Ìjẹ̀bú-Òde ti ìpínlẹ̀ Ògùn, Oloye Àjàó, S. Bọlaji Bakare, I.O. Àjànàkú Iléṣà, Olóyè T.A. Oni & ati àwọn ọmọ-kunrin rẹ ni Ìbàdàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Oṣinọwọ oní��òwò ọkọ̀ irinna ni Èkó, Mobọ́láji Bank-Anthony, Asábọ́rọ̀, ọmọ Ìkárọ̀ ni ẹ̀gbẹ́ Ọ̀wọ̀ ni ìpínlẹ̀ Ondo àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ ti wọn ti gbàgbé wọn pẹ̀lú ọrọ̀ ti wọn fi silẹ̀. Àwọn ti wọn ránti, ki ṣe nitori ọrọ̀ ti wọn fi silẹ̀ láyé ni èrò ránti ṣùgbọ́n àwọn ọmọ tó gba ẹ̀kọ́ ni ó lè jẹ ki wọn ṣe iránti wọn àti bi wọn ti lo ọrọ̀ na a fún lati ṣe oore fún àwọn aláìní. Àwọn Ọlọ́rọ̀ Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú kò kọ́ ọgbọ́n ninú itàn igbẹhin Ọba àti Ìjòyè ti kò lo ipò wọn dáradára, àwọn ti ó fi èrú kó ọrọ̀ jọ, tàbi ti ó lo ipò wọn lati fi tẹ ará ilú mọ́lẹ̀ ni àtijọ́. Irú ọrọ̀ bẹ́ ẹ̀ kò bá wọn kalẹ́ bẹni ìrántí wọn kò dára. Ni ọjọ́ keji ọ̀sẹ̀, ọjọ́ keje oṣù kẹfà, ọdún Ẹgbàá-lémẹ́rìndínlógún, ilé-iṣẹ́ Amóhùn-máwòrán Kẹrin ni Ilú-Ọba fi àpẹrẹ hàn bi àwọn ọmọ Ọlọ́rọ̀ lati Nigeria ti mba owó ninú jẹ́ ni Ilú-Ọba. Yorùbá ni “Ohun ti a kò bá jiyà fún, ki i lè tọ́jọ́”. Wọn nná owó ti ọgọrun enia lè ná ni ọdún kan ni alẹ́ ọjọ́ kan lai ronú ọ̀pọ̀ aláìní ni orílẹ̀ èdè wọn, ti Bàbá wọn ti fa ijiyà fún lati kó ọrọ̀ ti wọn nná dànù jọ. Kò si ìyàlẹ́nu ni irú iwà ti àwọn ọmọ ọlọ́rọ̀ Nigeria wọnyi hù nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn bàjẹ́, wọn kò ni ẹ̀kọ́, wọn kò mọ iyi owó nitori wọn kò ṣiṣẹ́ fun. Ọbabinrin Elizabeth Keji, pé aadọrun ọdún láyé ni ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kẹrin ọdún Ẹgbàálémẹrindinlólgún. Gbogbo ará ilú àti àwọn Ìjọ Onigbàgbọ́ pé jọ lati ṣe ayẹyẹ à ṣe pọ̀ fún Ọbabinrin ni ọjọ́ Ìsimi, ọjọ́ kejila, oṣù kẹfà ọdún. Eleyi bọ si àsikò ti ọkọ rẹ Philips pé ọgọrundinmarun ọdún. Lẹhin ti Ọbabinrin Elizabeth keji gun ori oyè ni ọdún mẹtalelọgọta sẹhin, ó bẹ ilú Èkó wò ni ọgọta ọdún sẹhin, nigbati Ilú Èkó jẹ́ Olú-Ilú orilẹ̀ èdè Nigeria ki a tó gba Òminira lábẹ́ Ilú-Ọba ni odun Ẹdẹgbaalelọgọta. A ṣe yi ṣe àmọ́dún o. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán wọnyi. Ìròyìn ikú Muhammad Ali ọmọ ọdún mẹ́rinlélaadọrin kàn ni oṣù kẹfa, ọjọ́ kẹta, ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún. Bi ó ti ẹ jẹ wi pé, Ali ti wà lóri àisàn fún bi ọgbọ̀n ọdún, inú ọmọdé àti àgbà ni àgbáyé ṣe ìdárò nigbati wọn gbọ ìròyìn ikú rẹ. Ki ṣe iṣẹ́ akànṣẹ́ nikan ni Muhammad Ali dúró fún, ó dúró fún ohun ti ó gbàgbọ́ lai bẹ̀rù. Ni bi ọdún marun-dinlọgọta sẹhin, nigbati Aláwọ-funfun ṣe òfin lati ya Aláwọ̀-dúdú si ọ̀tọ̀, pé wọn kò lè lo ohun amáyédẹrùn (bi ọkọ̀ wi wọ̀ pọ̀, ilé oúnjẹ, ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti bẹ́ ẹ̀ b ẹ́ ẹ̀ lọ) ti wọn pèsè fún ará ilú pẹ̀lú Aláwọ-funfun, Muhammad Ali kò pa ẹnu mọ lati dẹbi fún irú òfin àti iwà burúkú yi. Ó kọ̀ lati lọ jagun, ti kò gbàgbọ́ nitori ó gbàgbọ́ pé alafia dára ju ogun lọ. Muhammad Ali yi orúkọ ẹrú “Cacius Clay’’àti ẹ̀sìn padà lati kọ ẹ̀hin si iwà burúkú ti Aláwọ-funfun hù si enia rẹ. Muhammad Ali mú adùn wọ iṣẹ́ akànṣẹ́, ó fi ọlà rẹ ṣe àánú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ aláìní, ó si jẹ àwòkọ̀ṣe fún àwọn ọ̀dọ́ pàtàki Aláwọ̀-dúdú ti ó fi hà̀n pé ‘kò si ohun ti kò ṣe é ṣe, bi enia bá fi ọkàn si’. Eleyi jẹ ki èrò fẹ́ràn rẹ púpọ̀. Àwọn Olóri Ilú àti Ẹlẹ́sin ni oriṣiriṣi ati gbogbo àgbáyé ṣe ìdárò Muhammad Ali bi wọn ti ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin tó yẹ fún Ọba, ni ibi ìtẹ́ ìsìnkú ni oṣù kẹfa, ọjọ́ kẹwa, ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ, ọmọ-ọmọ, Ìyàwó, ẹbi àti ará ló gbẹ̀hin rẹ. Sùn re o. Ohun ti Yorùbá mọ̀ si àròkàn n irònú igbà gbogbo. Kò si ẹni ti ki ronú, ṣùgbọ́n àròkàn léwu. Inú rirò yàtọ si àròkàn. Inu rirò ni àwọn Onimọ-ijinlẹ̀ lò lati ṣe ọkọ̀ òfúrufú tàbi lọ si òṣùpá, oògùn igbàlódé lati wo àisàn, àti fún ipèsè ohun amáyédẹrùn igbàlódé yoku ṣùgbọ́n àròkàn lo nfa pi-pokùnso, ipàniyàn, olè jijà àti iwà burúkú miran. Bi èniyàn bá lówó tàbi wa ni ipò agbára kò ni ki ó má ro àròkàn nitori ìbẹ̀rù ki ohun ini wọn ma parẹ́, àisàn, ọ̀fọ̀, àjálù, à i ri ọmọ bi, ọmọ ti o n hùwà burúkú àti àwọn oriṣiriṣi idi miran. Bakan naa ni òtòṣì lè ni àròkàn nitori à i lówó lọ́wọ́ tàbi aini, àisàn, ọ̀fọ̀, ìrẹ́jẹ lati ọ̀dọ̀ ẹni ti ó ju ni lọ, ìrètí pi pẹ́ àti àwọn idi miran. Lára àmin àròk��n ni: à i lè sùn, à i lè jẹun, ìbẹ̀rù, ẹkún igbà gbogbo, ibànújẹ́ tàbi ọgbẹ́ ọkàn. Àròkàn kò lè tú nkan ṣe à fi ki ó bá nkan jẹ si. Ewu ti àròkàn lè fà ni: ẹ̀fọ́rí igbà gbogbo, aisan wẹ́rẹ-wẹ̀rẹ, aisan ẹ̀jẹ̀ riru, òyi àti àárẹ̀. Ni igbà miran kò si ohun ti èniyàn lè ṣe lati yẹ àròkàn pàtàki ẹni ti ọ̀fọ̀ ṣẹ, á ro àròkàn ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ igbà àwọn ohun miran wà ni ikáwọ́ lati ṣe lati din àròkàn kù. Lára ohun ti ẹni ti ó bá ni àròkàn lè ṣe ni: ki ó ni igbàgbọ́, ìtẹ́lọ́rùn, ro rere, ṣe iṣẹ rere, jinà si elérò burúkú tàbi oníṣẹ́ ibi àti lati fẹ́ràn ẹni keji. Ẹ̀tẹ̀ tó mbá ilú jà ni ‘iwà-ibàjẹ́’. Ìyà ti ará ilú njẹ lọ́wọ́lọ́wọ́, ki i ṣe èrè iwà-ibàjẹ́ ọdún kan, ṣùgbọ́n ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Kò si ìfẹ́ ilú, nitori eyi, àwọn oniwà ibàjẹ́ ni àwọn ará ilú nyin bi wọn bá ti ẹ fi èrú kó owó jọ pàtàki ni ilé ìjọ́sìn, wọn kò ri ẹni ba wọn wi. Fún akiyesi, ilé iṣẹ́ ti ó n pèsè iná mọ̀nàmọ́ná, owó ti Ìjọba àpa-pọ̀ ba pin lati pèsè iná mọ̀nàmọ́ná fún gbogbo ará ilú, ọ̀gá ilé-iṣẹ́ á pin pẹ̀lú àwọn Ìjọba Ológun tàbi Òṣèlú Alágbádá. Ni bi ọgbọ̀n ọdún sẹhin, nigbati àwọn ọmọ iṣẹ́ ri pé àwọn ọ̀gá ti ó nji owó, kò si ẹni ti ó mú wọn, àwọn na a brẹ̀rẹ̀ si lọ yọ nkan lára ẹ̀rọ ti ó gbé iná wọ àdúgbò lati lè gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ará àdúgbò. Ará àdúgbò á dá owó ki àwọn òṣiṣẹ́ ilé-iṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná tó wá tú ohun ti ó bàjẹ́ tàbi ohun ti wọn yọ ṣe. Kàkà ki ará ilú para-pọ̀ lati wo ẹ̀tẹ̀ san, nipa gbi gbé ogun ti iwà-ibàjẹ́ ni ilé-iṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná, onikálùkù bẹ̀rẹ̀ si ṣètò fún ará wọn nipa ri ra ẹ̀rọ́ iná mọ̀nàmọ́ná ti àwọn Òyinbó ngbe dani nigbati wọn bá fẹ lọ pàgọ́. Àwọn ẹ̀rọ wọnyi kò lágbára tó lati dipò iná mọ̀nàmọ́ná ti ó yẹ ki Ìjọba pèsè. Àwọn ará ilú kò ro ìnáwó ti ó kó wọn si, ariwo, àti èéfín burúkú ti ẹ̀rọ yi nfẹ sinú afẹ́fẹ́. Àwọn ti ó nja ilú lólè ni ó nkó ẹ̀rọ wọnyi wọlé, wọn kò gbèrò ki iná mọ̀nàmọ́ná wa nitori wọn kò ni ri ẹni ra ọjà wọn. Wọn rò wi pé àwọn lè dá ilé-iṣẹ́ ti ó n pèsè iná mọ̀nàmọ́ná silẹ̀ ti ó lè lo atẹ́gùn, omi, epo rọ̀bì, oòrùn lati pèsè iná ti kò léwu bi ẹ̀rọ́ iná mọ̀nàmọ́ná. Ẹ̀tẹ̀ ṣòro lati wòsàn ju làpálàpá lọ, ibàjẹ́ ló yára lati ṣe ju lati tú nkan ṣe lọ. O ye ki ará ilú para pọ̀ pẹ̀lú Ìjọba lọ́wọ́lọ́wọ́, lati gbé ogun ti iwà ibàjẹ́ àti àwọn aṣèbàjẹ́, ju pé ki wọn fi ara gbi gbóná kọ ìyà ọgbọ̀n ọdún laarin ọdún kan tàbi meji. Ìròyìn ti o jade ni ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹwa, oṣú karun, ọdún Ẹgbàá-le-mẹ́rìndínlógún, sọ wi pé Olóri Òṣèlú Ilú Ọba, David Cameron pe orilẹ̀ èdè Nigeria ni ilú ti ó hu iwà ibàjẹ́ jù ni àgbáyé. Kò ṣe àlàyé bi Ì̀jọba ilú rẹ ti ngba owó iwà ibàjẹ́ pamọ́ lati fi tú ilú wọn ṣe. Ẹni gbé epo lájà, bi kò bá ri ẹni gba a pamọ́, kò ni ya lára lati tún ji omiran. Bi kò ri ẹni gba a, ó lè jẹ epo na a tàbi ki ẹni tó ni epo ri mú ni wéré. Gẹgẹ bi òwe Yorùbá ti sọ pé “Ẹni gbé epo lájà, kò jalè̀ tó ẹni gba a”, bi àwọn ti ó n fi ọna èrú àti iwà ibàjẹ́ ja ilú lólè, kò bá ri àwọn Ilú Ọba gba owó iwà ibàjẹ́ lọ́wọ́ wọn, iwá burúkú á din kù. Ogun ti Ìjọba tuntun ni Nigeria gbé ti iwà ibàjẹ́ lati igbà ti ará ilú ti dibò yan Ìjọba tuntun -Muhammadu Buhari àti Yẹmi Osinbajo, ni bi ọdún kan sẹhin ni lati jẹ ki àwọn tó hu iwa ibaje jẹ èrè iṣẹ́ ibi, ki wọn si gba owó iwà ibàjẹ́ padà si àpò ilú. Eyi ti ó ṣe pàtàki jù ni ki Ìjọba Ilú Ọba ṣe àlàyé bi wọn yio ti da àwon owó Nigeria padà ni ipàdé gbi gbógun ti iwa ibaje, ki wọn lè fihan pé àwọn kò fi ọwọ́ si iwà ibàjẹ́. Ìbá ṣe pọ̀ laarin Yorùbá àti Ìlú-Ọba ti lé ni igba ọdún nitori òwò Òkè-òkun, pàtàki òwò ẹrú àti fún ẹ̀kọ́ ni ilé iwé giga. Nitori eyi, àṣà àti èdè Yorùbá kò ṣe fi ọwọ́ rọ sẹhin. Ni Ilú-Ọba, ẹ̀tọ́ ará ilú ni ki Ìjọba pèsè ohun amáyédẹrùn, pàtàki ibùgbé fún ọmọ ilú, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́ fún ọmọ àti ará ilú. Àwọn ẹ̀tọ́ wọnyi kò tọ́ si àlejò, ẹni ti ó fi èrú wọ ilú ti kò ni àṣẹ igbelu, tàbi ẹni tó ni iwé lati ṣe iṣẹ ṣùgbọ́n ko ti i di ará ilú. Ẹni ti ó ni iwé-igbelu lati ṣe iṣẹ́ ti ko ti di ará ilú kò ni ẹ̀tọ́ si ilé Ìjọba, ṣùgbọ́n wọn ni ẹ̀tọ́ si ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́. Iwé ìròyìn irọlẹ, gbe jade bi Trudy Alli-Balogun, ti lo ipò rẹ ni ilé iṣẹ́ ti ó nṣe ipèsè ibùgbé fún ọmọ ilú, lati gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Yorùbá ti kò ni ẹ̀tọ́ si irú ilé bẹ́ ẹ̀. Wọn ṣe ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún marun fún. Ìròyìn ti ó gbòde ni inu iwé ìròyìn àti lori ayélujára fi han bi àwọn Olóri Òṣèlú, Aṣòfin àgbà nla àti kékeré, òṣiṣẹ́ Ìjọba àgbà àti àwọn ti ó wà ni ipó giga ni Nigeria ti lo ipò wọn lati fi ja ilu lólè. Àyipadà ni Ìjọba pẹ̀lú pe Olóri Òṣèlú Muhammadu Buhari/Yẹmi Osinbajo ti ó gbógun ti iwà ibàjẹ́, ló jẹ ki àṣiri iṣẹ́ ibi wọnyi jade si ará ilú bi àwọn ti ó wà ni ipò giga ti nlo ipò lati fi hu iwà ibàjẹ́ nitori àti kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà ẹ̀bùrú. Yorùbá sọ wi pé “Ìṣe ilé ló mbá ni dode”. Ni àtijọ́, àṣà Yorùbá ni lati wá idi bi enia ti kó ọrọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ni ayé òde oni, olówó ni wọ́n mbọ, bi ó bá ti ẹ jalè tàbi ti ẹ̀wọ̀n de nitori iṣẹ́ ibi. Àyipadà burúkú yi ni obìnirin Trudy Alli-Balogun gbé dé ẹnu iṣẹ́ lati ja ilé iṣẹ́ rẹ ni olè ọ̀kẹ́ aimoye, ti ó si na owó bẹ́ ẹ̀ ni ìná àpà lai ronú orúkọ burúkú ti ó rà fún Yorùbá àti gbogbo orilẹ̀ èdè Nigeria ni Ilú-Ọba àti pé irú iwà ibàjẹ́ yi ló ba ohun amáyédẹrùn jẹ ni Nigeria. Iwà ibàjẹ́ kò ni orúkọ meji, ẹni ba jalè ba ọmọ jẹ́. Yorùbá fẹ́ràn ayẹyẹ ṣi ṣe púpọ̀ pàtàki fún igbéyàwó. Ni ayé àtijọ́, ìnáwó igbéyàwó kò tó bi ó ti dà ni ayé òde òni. Titi di bi ogoji ọdún sẹhin, ilé Bàbá Iyàwó tàbi ọgbà ẹbi ni wọn ti nṣe àpèjọ igbéyàwó. Ẹbi ọ̀tún àti ti òsi yio joko fún ètò igbéyàwó lati gba ẹbi ọkọ ni àlejò fún àdúrà gbi gbà fún àwọn ọmọ ti ó nṣe igbéyàwó àti lati gbà wọn ni ìyànjú bi ó ṣe yẹ ki wọn gbé pọ̀ ni irọ̀rùn. Ẹbi ọkọ yio kó ẹrù ti ẹbi iyàwó ma ngbà fún wọn, lẹhin eyi, ẹbi iyàwó yio pèsè oúnjẹ fún onilé àti àlejò. Onilù àdúgbò lè lùlù ki wọn jó, ṣùgbọ́n kò kan dandan ki wọn lu ilu tàbi ki wọn jó. Nigbati ìnáwó rẹpẹtẹ fún igbeyawo bẹ̀rẹ̀, àwọn ẹlòmíràn bẹ̀rẹ̀ si jẹ igbèsè lati ṣe igbéyàwó pàtàki igbéyàwó ti Olóyìnbó ti a mọ si igbéyàwó-olórùka. Nitori àṣejù yi, olè bẹ̀rẹ̀ si jà ni ibi igbéyàwó, eyi jẹ́ ki wọn gbé àpèjẹ igbéyàwó àti àwọn ayẹyẹ yoku kúrò ni ilé. Wọn bẹ̀rẹ̀ si gbé àpèjẹ lọ si ọgbà ilé-iwé, ilé ìjọ́sìn tàbi ọgbà ilú àti ilé-ayẹyẹ. Yorùbá fẹ́ràn ayẹyẹ ṣi ṣe púpọ̀, ṣùgbọ́n àṣà tó gbòde ni ayé òde òni, ni igbéyàwó àti ayẹyẹ bi ọjọ́ ìbí ṣi ṣe ni òkèrè. Gẹgẹ bi àṣà Yorùbá, ibi ti ẹbi iyàwó bá ngbé ni ẹbi ọkọ yio lọ lati ṣe igbéyàwó. Ẹni ti kò ni ẹbi àti ará tàbi gbé ilú miran pàtàki Òkè-Òkun/Ilú Òyìnbó, yio lọ ṣe igbéyàwó ọmọ ni òkèrè. Wọn yio pe ẹbi àti ọ̀rẹ́ ti ó bá ni owó lati bá wọn lọ si irú igbéyàwó bẹ́ ẹ̀. Ẹbi ti kò bá ni owó, kò ni lè lọ nitori kò ni ri iwé irinna gbà. A ri irú igbéyàwó yi, ti ẹbi ọkọ tàbi ti iyàwó kò lè lọ. Eleyi wọ́pọ laarin àwọn Òṣèlú, Ọ̀gá Òṣìṣẹ́ Ìjọba àti àwọn ti ó ri owó ilú kó jẹ. Igbéyàwó àti ayẹyẹ ṣi ṣe ni òkèrè, jẹ́ ikan ninú àṣà ti ó mba owó ilú jẹ́. Lati kúrò ni ilú ẹni lọ ṣe iyàwó tàbi ayẹyẹ ni ilú miran, wọn ni lati ṣẹ́ Naira si owó ilu ibi ti wọn ti fẹ́ lọ ṣe ayẹyẹ, lẹhin ìnáwó iwé irinna àti ọkọ̀ òfúrufú. Ilú miran ni ó njẹ èrè ìnáwó bẹ́ ẹ̀, nitori bi wọn bá ṣe e ni ilé, èrò púpọ̀ ni yio jẹ èrè, pàtàki Alásè àti Onilù. A lérò wi pé ni àsìkò ọ̀wọ́n owó pàtàki owó òkèrè ni ilú lati ṣe nkan gidi, ifẹ́ iná àpà fún ayẹyẹ á din kù. Ìbẹ̀rù tó gbòde ayé òde òni ni pé “Ayé Móoru”, nitori iṣẹ̀lẹ̀ ti o nṣẹlẹ̀ ni àgbáyé bi òjò àrọ̀ irọ̀ dá ni ilú kan, ilẹ̀-riru ni òmìràn, ọ̀gbẹlẹ̀, omíyalé, ijà iná àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ. Eleyi dá ìbẹ̀rù silẹ̀ ni àgbáyé pàtàki ni àwọn ilú Òkè-Òkun bi Àmẹ́ríkà ti ó ka àwọn iṣẹ̀lẹ̀ wọnyi si àfọwọ́fà ọmọ ẹda. Wọn kilọ̀ pé bi wọn kò bá wá nkan ṣe si Ayé Móoru yi, ayé yio parẹ́. Àpẹrẹ miran ti a lè fi ṣe àlàyé pé “Ọ̀run nyabọ̀, ki ṣé ọ̀rọ̀ ẹnìkan”, ni ẹni ti ó sọ pé ohun ri amin pé ayé ti fẹ parẹ́, àwọn kan gbàgbọ́, wọn bẹ̀rẹ̀ si ta ohun ìní wọn. Àti ẹni ti ó ta ohun ìní àti ẹni ti ó ra, kò si ninú wọn ti ó ma mú nkankan lọ ti ayé bá parẹ ni tootọ. Elòmíràn, kò ni ṣe iwadi ohun ti àwọn èniyàn fi ńsáré, ki ó tó bẹ̀rẹ̀ si sáré. Ọpọlọpọ ti sa wọ inú ewu ti wọn rò wí pé àwọn sá fún. Fún àpẹrẹ, nigbati iná ajónirun balẹ̀ ni àgọ́ Ológun ni Ikẹja ni ìlú Èkó ni bi ọdún mẹwa sẹhin. Bi àwọn kan ti gbọ́ ìró iná ajónirun yi, wọn sáré titi ọpọ fi parun si inú irà ni Ejigbo ni ọ̀nà jínjìn si ibi ti ìṣẹ̀lẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Òwe Yorùbá yi ṣe gba àwọn ti o nbẹ̀rù nigba gbogbo níyànjú wí pé ó yẹ ki èniyàn fara balẹ̀ lati ṣe iwadi ohun ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀ ki ó tó “kú sílẹ̀ de ikú”. Bi èniyàn bẹ̀rù á kú, bi kò bẹ̀rù á kú, nitori gẹ́gẹ́ bi itàn àdáyébá, gbogbo ohun ti ó nṣẹlẹ̀ láyé òde òni ló ti ṣẹlẹ̀ ri. Àṣà Yorùbá ma ńri ọpẹ́ ninú ohun gbogbo, nitori eyi ni àjọyọ̀ àti ayẹyẹ ṣe pọ ni ilẹ̀ Yorùbá. Bi kò bá ṣe ayẹyẹ igbéyàwó; á jẹ́ idúpẹ́ fun ikómọ/isọmọlórúkọ; ìsìnku arúgbó; ikóyọ ninú ewu ijàmbá ọkọ̀; iṣile; oyè gbigbà ni ilé-iwé giga tàbi oyé ilú; idúpẹ́ ìparí ọdún tàbi ọdún tuntun àti bẹ̃bẹ̃ lọ. Kò si igbà ti àlejò kò ni ri ibi ti wọn ti ńṣe ayẹyẹ kan tàbi èkeji ni gbogbo ilẹ́ Yorùbá. Eyi jẹ́ ki àlejò rò wipé igbà gbogbo ni Yorùbá fi ńṣọdún. Kò si ẹni ti o ńdúpẹ́ ti inú rẹ ńbàjẹ́, tijó tayọ̀ ni enia fi nṣe idúpẹ́. Ninú idúpẹ́ àti àjọyọ̀ yi ni ẹni ti inu rẹ bàjẹ́ miran ti lè ni ireti pé ire ti ohun naa yio dé. Ni ilú Èkó, lati Ọjọ́bọ̀ titi dé ọjọ́ Àikú ni enia yio ri ibi ti wọn ti ńṣe ayẹyẹ. Ọjọ́bọ̀ jẹ ọjọ́ ti wọn ńṣe àisùn-òkú; ọjọ́ Ẹti ni isinkú, ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ti ayẹyẹ igbéyàwó nigbati ọjọ́ Àikú wà fún idúpẹ́ pàtàki ni ilé ijọsin onigbàgbọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayẹyẹ yi ló mú ipèsè jijẹ, mimu, ilù àti ijó lati ṣe àlejò fún ẹbi, ará àti ọ̀rẹ́ ti ó wá báni ṣe ayẹyẹ. A lè fi òwe Yorùbá ti ó ni “A ò mọ èyi ti Ọlọrun yio ṣe, kò jẹ́ ki á binú kú”, tu ẹni ti ó bá ni ìrẹ̀wẹ̀sì ninú, pé ọjọ́ ọ̀la yio dára. Yorùbá gbàgbọ́ pé ẹni ti kò ri jẹ loni, bi kò bá kú, ti ó tẹpá-mọ́ṣẹ́, lè di ọlọ́rọ̀ ni ọ̀la. Nitori eyi, kò yẹ ki enia “Kú silẹ̀ de ikú” nitorina, “Bi ẹ̀mi bá wà, ireti ḿbẹ”. À ì sí Iná Mọ̀nà-mọ́ná àti Epo Ọkọ̀ bá Onílé pẹ̀lú Àlejò. Ki gbogbo Nigeria tó gba ominira ni àwọn Òṣèlú lábẹ́ olùdari Olóyè Ọbáfẹ́mi Awolọwọ ti fi owó kòkó àti iṣẹ́-àgbẹ̀ dá nkan ṣe fún gbogbo ilẹ̀ Yorùbá. Yorùbá jẹ èrè àwọn ohun gidi, amáyé-dẹrùn bi ilé-iwé ọ̀fẹ́, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé iṣẹ́ amóhùn-máwòrán àkọ́kọ́, ilé àwọn àgbẹ̀ (olókè mẹrin-lé-lógún – ilé giga àkọ́kọ́), ọ̀nà ọlọ́dà, omi, iná mọ̀nà-mọ́ná àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ohun ipèsè wọnyi jẹ èrè lati ọ̀dọ̀ Òṣèlú tó fẹ́ràn ilú ti ó gbé wọn dé ipò, eleyi jẹ àwò kọ́ iṣe fún àwọn Òṣèlú ẹ̀yà ilẹ̀ Nigeria yókù. Ìjọba Ológun fi ibọn àti ipá gbé ara wọn si ipò Òṣèlú, wọn fi ipá kó gbogbo ohun amáyé-dẹrùn si abẹ́ Ìjọba àpapọ̀. Lati igbà yi ni ilé-iwé kékeré àti giga, ilé-ìwòsàn àti ohun amáyé-dẹrùn ti Òṣèlú pèsè fún agbègbè wọn ti bẹ̀rẹ̀ si bàjẹ́. A lè fi ibàjẹ́ ohun amáyé-dẹrùn ti àwọn Òṣèlú àkọ́kọ́ pèsè fún ara ilú wọnyi wé ọbẹ̀ tó dànu,̀ ti igbẹhin rẹ já si òfò fún onilé àti àlejò. Òwe Yorùbá ni “Ọbẹ̀ tó dànù, òfò onilé, òfò àlejò” Àpẹrẹ pataki ni ọna àti ilé-iwosan ti ó bàjẹ́. Òfò ni ọ̀nà ti ó bàjẹ́ mú bá ara ilú nipa ijàmbá ọkọ̀ fún onilé àti àlejò. Ibàjẹ́ ile-iwosan jẹ òfò fún onilé àti àlejò nitori ọ̀pọ̀ àisàn ti kò yẹ kó pani ló ńṣe ikú pani, fún àpẹrẹ, itijú ni pé, Ọba, Ìjòyè àti Òṣèlú ńkú si àjò fún àìsàn ti kò tó nkan. Dákú-dáji iná mọ̀nà-mọ́ná ti ó sọ ilú si òkùnkùn jẹ́ òfò fún olówó àti aláini nitori, yàtọ̀ si ariwo àti òórùn, ai mọye enia ni ikú ẹ̀rọ mọ̀nà-mọ́ná ti pa. À ì sí Iná Mọ̀nà-mọ́ná àti Epo Ọkọ̀ bá Onílé pẹ̀lú Àlejò. Ìwà ìbàjẹ́, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ló da ọbẹ̀ ohun amáyédẹrùn danu. Bi ọbẹ̀ bá dànù, kò ṣe kó padà, à fi ki enia se ọbẹ̀ tuntun, bi ó bá fẹ jẹ ọbẹ̀. Yorùbá ni “Ẹ̀bẹ̀ là nbẹ òṣikà, ki ó tú ilú ṣe”. Fún àtúnṣe, ó ṣe pàtàki ki gbogbo ará ilú parapọ̀ lati tún ohun ti ó ti bàjẹ́ ṣe nipa gbi gbé ogun ti iwà ìbàjẹ́ àti àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà. Odò ti ó bá gbàgbé orisun gbi gbẹ ló ngbẹ Orúkọ idile Yorùbá ti ó nparẹ́ nitori èsìn. Àwọn orúkọ ìdílé wọnyi kò di ẹlẹ́sìn lọ́wọ́ lati ṣe iṣẹ́ rere tàbi dé ọ̀run, Ni igbà àtijọ́, ẹranko ti wọn pè ni Ẹkùn jẹ alágbára ẹranko, bẹni Kìnìún si jẹ́ alágbára ẹranko. Bi Kìnìún ti lágbára tó ninú igbó, bi ó bá bú ramúramù, ohun gbogbo ninú igbó á pa kẹ́kẹ́ titi dé ori ẹranko yoku. Ti Ẹkùn nikan ló yàtọ̀, nitori Ọlọrun fún ni ẹ̀bùn igbóyà, idi niyi ti a fi ńpè ni “Baba Ẹranko”, ti a ńpè Kìnìún ni “Ọlọ́là Ijù”. Ẹ̀rù ló sọ ọmọ Ẹkùn di Ológbò/Ológìní tó fi di Ẹran-àmúsìn – Ọdẹ peku-peku Ni ọjọ́ kan, Ẹkùn gbéra lọ sinú igbó lati lọ wa oúnjẹ fún àwọn ọmọ rẹ, àwọn ọmọ ẹ kéré wọn kò lè yára bi iyá wọn. Ó fún wọn ni imọ̀ràn pe ki wọn kó ara pọ̀ si ibi òkiti-ọ̀gán ti ohun ti lè tètè ri wọn, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù fún ohunkóhun tàbi ẹranko ti ó bá wá si sàkáni wọn. Gẹgẹ bi a ṣe mọ, Kìnìún àti Ẹkùn, ọ̀gá ni onikálùkù láyé ara wọn, wọn ki ja. Ibi ti Kìnìún bá wà Ẹkùn kò ni dé ibẹ̀, ibi ti Ẹkùn bá wà Kìnìún ò ni dé ibẹ̀. Nitori èyi ni Yorùbá fi npa lowe pé “Kàkà ki Kìnìún ṣe akápò Ẹkùn, onikálùkù yio má ba ọdẹ rẹ̀ lọ”. Lai fà ọ̀rọ̀ gùn àwọn ọmọ Ẹkùn gbọ́ igbe Kìnìún, wọn ri ti ó ré kọja, àwọn ọmọ Ẹkùn ti ẹ̀rù ba ti kò ṣe bi iyá wọn ti ṣe ìkìlọ̀, ìjáyà bá wọn, wọ́n sá. Nigbati Ẹkùn dé ibùdó rẹ lati fún àwọn ọmọ rẹ ni ẹran jẹ, àwọn ọmọ rẹ kò pé, ṣ̀ugbọ́n àwọn ọmọ ti ijáyà bá padà wá bá iyá wọn, nigbà yi ni iyá wọn rán wọn leti ikilọ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jáyà. Nitori èyi, ohun kọ̀ wọ́n lọ́mọ. Nigbati iyá wọn kọ̀ wọ́n lọ́mọ, wọn kò lè ṣe ọdẹ inú igbó mọ́, wọn di ẹranko tó ńrágó, ti wọn ńsin ninú ilé, to ńpa eku kiri. Idi èyi ni Yorùbá fi npa ni òwe pé “Ìjayà ló bá ọmọ Ẹkùn ti ó di Ológbò ti ó ńṣe ọde eku inú ilé. Ẹ̀kọ́-ìṣirò ni èdè Yorùbá Yorùbá ni bi wọn ti ma nṣe ìṣirò ki wọn tó bẹ̀rẹ̀ si ka ni èdè Gẹ̀ẹ́sì. Akọ̀wé yi kọ ìṣirò ki ó tó bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé lọdọ ìyá rẹ̀ àgbà. Nígbàtí ìyá-àgbà bá nṣe iṣẹ́ òwú “Sányán” lọ́wọ́, a ṣa òkúta wẹ́wẹ́ fún ọmọ-ọmọ rẹ̀ lati ṣe ìṣirò ni èdè Yorùbá. Is̀irò ni èdè Yorùbá ti fẹ́ di ohun ìgbàgbé, nitori àwọn ọmọ ayé òde òní kò rí ẹni kọ́ wọn ni ilé tàbi ilé-ìwé, nitorina ni a ṣe ṣe àkọọ́lẹ̀ ìṣirò yi si ojú ewé yi. Yorùbá ni bi wọn ti ma a nka nkàn ki wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ si ka a ni èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ẹ ṣe àyẹ̀wò kíkà ni èdè Yorùbá ni ojú ewé yi: Ẹ Kú Ọwọ́ Lómi Là Nki Ọlọ́mọ Tuntun – Ìtọ́jú Ọmọ Tuntun ni Àtijọ́ Ni ayé àtijọ́, kò si itẹdi à lò sọnù bi ti ayé òde òni. Bẹni wọn kò lo ìgò oúnjẹ lati fún ọmọ tuntun ni oúnjẹ. Ọwọ́ ọlọ́mọ tuntun ki kúrò ni omi nitori omi ni wọn fi nto àgbo ti wọn nrọ ọmọ fún ìtọ́jú ọmọ tuntun. Aṣọ àlòkù Bàbá, Ìyá àti ẹbi ni wọn nya si wẹ́wẹ́ lati ṣe itẹdi ọmọ nitori kò si itẹdi à lò sọnú bi ti ayé òde òni. Ọmọ tuntun a ma ya ìgbẹ́ àti ìtọ̀ tó igbà mẹwa tàbi jù bẹ́ ẹ̀ lọ ni ojúmọ́. Ọmọ ki i sùn ni ọ̀tọ̀, ẹ̀gbẹ́ ìyá ọmọ ni wọn ntẹ́ ọmọ si. Lẹhin ọsẹ̀ mẹ́fà tàbi ogoji ọjọ́ tàbi ó lé kan ti wọn ti bi ọmọ, ìyá àti ọmọ lè lọ òde, ìyá á pọn ọmọ lati jáde. Nitori aṣọ ni itẹdi kò gba omi dúró, bi ọmọ bá tọ̀ tàbi ya ìgbẹ́, á yi aṣọ ìyá tàbi ẹni ti ó gbé ọmọ. Kò si ẹ̀rọ ifọṣọ igbàlódé nitori na a, ó di dandan ki wọ́n fọ aṣọ ọmọ àti ẹni ti ó gbé ọmọ ni igbà gbogbo ni ilé ọlọ́mọ tuntun. Eyi ni ó jẹ́ ki Yorùbá ma ki ẹni ti ó bá ntọ ọmọ lọ́wọ́ pé “Ẹ kú ọwọ lómi nitori ọwọ́ ki kúrò ni omi aṣọ fí fọ̀. Òṣèlú Nigeria, Ẹ Jọ̀wọ́, Ẹ Má Pe Ajá ni Ọ̀bọ fún Ará Ìlú Lati bi ogójì ọdún sẹhin, Epo-rọ̀bi nikan ni okùn ọrọ̀ ajé orilẹ̀ èdè Nigeria, ó si ti pa owó ribiribi wọlé fún ilú. Nigbati Epo-rọ̀bi bẹ̀rẹ̀ si pa owó wọlé, ará ilú kọ iṣẹ́ àgbẹ̀ àti àwọn ohun ti ilú nṣe silẹ̀ fún ifẹ́ ọjà òkèrè. Àsikò Epo-rọ̀bi ni ilú fi irẹsi òkèrè dipò oriṣiriṣi oúnjẹ ilẹ̀ wa. Ki ṣe eyi nikan, Ìjọba Ológun àti Òṣèlú bẹ̀rẹ̀ iwà ibàjẹ́ nipa ki kó owó ti ó yẹ ki wọn fi tún ilú ṣe jẹ. Wọn ò kó owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yi dúró ni ilú, wọn nko lọ si Òkè-Òkun, eyi ló ba iná mọ̀nàmọ́ná, ilé-ìwòsàn, ilé-iwé, ọ̀nà, omi mi-mun àti ohun amáyédẹrùn yoku jẹ́. Lẹhin ti àwọn Ìjọba Ológun àti Òṣèlú fi ipò wọn ba ilú jẹ́ tán, bi ori bá fọ́ wọn, wọn á gba ọ̀nà Òkè-Òkun lọ fún ìtọ́jú, dipò ki wọn tú ile-iwé ṣe, wọn a fi owó ti wọn ji pamọ́ rán ọmọ lọ si Òkè-Òkun fún ẹ̀kọ́ ti ó yè kooro. Wọn a fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ́ ra ilé nla si Òkè-Òkun, oúnjẹ àti èso ilú kò dùn lẹnu olówó, aṣọ àti ohun ti ará ilú nṣe kò dára tó, ọjà Òkè-Òkun nikan ni wọn lè fi yangàn. Lai pẹ yi, àwọn Òṣèlú bẹ̀rẹ̀ si polongo pé “ki ará́ ilu ra ọja ilú, ki Naira (owo Nigeria) lè gòkè”. Ki i ṣe ìyànjú burúkú ni eyi ṣùgbọ́n, “ọ̀rọ̀ kò dùn lẹ́nu olè”, kì í ṣe lati ẹnu àwọn Òṣèlú ti ẹnu wọn ti fẹ si ọjà òkèrè nitori wọn ti kó owó ilú pamọ́ si àwọn ilú Òkè-Òkun. Bi a bá ṣe akiyesi, ki àṣiri tó tú ni àsikò Ìjọba tuntun (Buhari/Òṣinbàjò), àwọn ti ilé-iṣẹ́ Agbógun ti ìwà ìbàjẹ́ tọka tàbi mú pé ó kó owó ilú jẹ jù̀, kò wọ aṣọ Òkè-Òkun. Ó san ki wọn wọ aṣọ Òkè-Òkun, ju ki wọn kó owó rẹpẹtẹ ti wọn ji kó lọ si Òkè-Òkun. Díẹ̀ ninú àwọn Òṣèlú ti Ilé Iṣẹ́ Agbógun ti Ìwà Ìbàjẹ́ fi ẹ̀sùn kàn Ẹ̀bẹ̀ la bẹ̀ “Òṣèlú Nigeria” ki wọn ma pe Ajá l’Ọbọ fún ará ilú, ki wọn kó owó ilú ti wọn ji pamọ́ si Òkè-Òkun padà, ki wọn si fi àpẹrẹ rere silẹ̀ fún ará ilú nipa àyipadà kúrò ni iwà ojúkòkòrò àti olè ti wọn nfi ipò jà dúró. Àyipadà Òṣèlú kúrò ninú iwà burúkú ni ó lè mú ki owó ilú (Naira) kògè. “Awọ kò ká Ojú ìlù, Ọmọ Onílù ni òhun fẹ́ má a sun Awọ jẹ – Ojúkòkòrò àwọn Òṣèlú Nigeria”: Nigbati àwọn Òṣèlú gba Ìjọba ni igbà keji lọ́wọ́ Ìjọba Ológun, inú ará ilú dùn nitori wọn rò wi pé Ológun kò kọ iṣẹ́ Òṣèlú. Ilú rò wi pé Ìjọba Alágbádá yio ni àánú ilú ju Ìjọba Ológun lọ. Ó ṣe ni laanu pé fún ọdún mẹ́rìndínlógún ti Òṣèlú ti gba Ìjọba, wọn kò fi hàn pé wọn ni àánú ará ilú rárá. Dipò ki wọn ronú bi nkan yio ti rọrùn fún ilú nipa ipèsè ohun amáyédẹrùn bi iná mọ̀nàmọ́ná, ilé-iwé, ilé-ìwòsàn, ojú ọ̀nà ti ó dára, òfin lati jẹ ki ilú tòrò, ṣe ni wọn bẹ̀rẹ̀ si ji owó ilú. Bi ori bá fọ́ Òṣèlú, wọn á lọ si Òkè-Òkun nibiti wọn kó owó ti ó yẹ ki wọn fi tú ilé-ìwòsàn ṣe si. Àwọn Òṣèlú Òkè-Òkun nfi owó Nigeria tọ́jú ará ilú wọn nitori eyi, gbogbo ọ̀dọ́ Nigeria ti kò ni iṣẹ́ fẹ́ lọ si Òkè-Òkun ni ọ̀nà kọnà. Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé “Awọ kò ká Ojú ìlù, Ọmọ Onilù ni òhún fẹ́ má a sun Awọ jẹ” bá ìròyìn ti ó jáde ni lọ́wọ́-lọ́wọ́, bi àwọn Òṣèlú ti bá owó ọrọ̀ ajé Nigeria jẹ nipa bi wọn ti ṣe pin owó ohun ijà fún Ológun lati ra ibò. ‘Epo Rọ̀bì’ ni ‘Awọ’ nitori ó lé ni idá ọgọrin ti owó epo rọ̀bì kó ni owó ọrọ̀ ajé ti ilú tà si Òkè-Òkun. Fún bi ọdún mẹ̃dógún ninú ọdún merindinlogun ti Èrò Ẹgbẹ́ Òṣèlú (ti Alágboòrùn) fi ṣe Ìjọba ki ó tó bọ lọ́wọ́ wọn ni ọdún tó kọjá, owó epo rọ̀bì lọ si òkè rẹpẹtẹ, ọrọ̀ ajé yoku pa owó wọlé. Dipò ki wọn lo owó ti ó wọlé lati tú ilú ṣe, wọn bẹ̀rẹ̀ si pin owó lati fi ra owó Òkè-Òkun lati kó jade lọ ra ilé nlá si àwọn ilú wọnyi lati sá fún ilú ti wọn bàjẹ́ ni gbogbo ọ̀nà. Owó epo rọ̀bì fọ́, awọ kò wá ká ojú ilú mọ́. Oníṣẹ́ Ìjoba kò ri owó-oṣ̀ù gbà déédé, àwọn ti ó fi ẹhin ti ni iṣẹ́ Ìjọba kò ri owó ifẹhinti wọn gba, owó ilú bàjẹ́, bẹni àwọn Òṣèlú bú owó oṣ́u rẹpẹtẹ fún ara wọn. Eyi ti ó burú jù ni owó rẹpẹtẹ miran ti wọn bù lati ra ọkọ ti ìbọn ò lè wọ, olówó nla lati Òkè-Òkun fún Ọgọrun-le-mẹsan Aṣòfin-Àgbà. Olóri Aṣòfin-Àgbà fẹ ra ọkọ̀ mẹsan fún ara rẹ nikan. Àsìkò tó ki àwọn èrò ji lati bá àwọn olè wọnyi wi, nitori àwọn Òṣèlú Òkè-Òkun nibiti wọn nkó owó ilú lọ, kò fi owó ilú wọn tọ́jú ara wọn, wọn nwọ ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ilú, àyè kò si fún wọn lati ja ilú ni olè bi ti àwọn Òṣèlú Nigeria. Olóri Ẹbi, Baba Bùkátà Olóri Ẹbi jẹ àkọ́bi ọkùnrin ni idilé. Bi àkọ́bi bá kú, ọkùnrin ti ó bá tẹ̀le yio bọ si ipò. Iṣẹ́ olóri ẹbi ni lati kó ẹbi jọ fún ilọsiwájú ẹbi, nipa pi pari ijà, ijoko àgbà ni ibi igbéyàwó, ìsìnkú, pi pin ogún, ìsọmọ-lórúkọ, ọdún ìbílẹ̀ àti ayẹyẹ yoku. Ni ayé òde òni, wọn ti fi owó dipò ipò àgbà, nitori ki wọn tó pe olóri ẹbi ti ó wà ni ìtòsí, wọn yio pe ẹni ti ó ni owó ninú ẹbi ti ó wà ni òkèrè pàtàki ti ó bá wà ni Èkó àti àwọn ilú nla miran tàbi Ilú-Òyinbó/Òkè-Òkun. Ai ṣe ojúṣe Ìjọba nipa ipèsè ilé-iwòsàn ti ó péye, Ilé-iwé, omi mimu àti ohun amáyédẹrùn yoku jẹ ki iṣẹ́ pọ fún olóri ẹbi. Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ wi pé “Olóri Ẹbi, Baba Bùkátà”, iṣẹ́ nla ni lati jẹ Olóri Ẹbi, ó gba ọgbọ́n, òye àti ìnáwó lati kó ẹbi jọ. A ki yin lati Ilé Ni ai pẹ yi, Olùkọ̀wé yi bẹ ilé wò fún bi ọ̀sẹ̀ mẹta. A ṣe àwọn akiyesi wọnyi. Ilú Èkó n fẹ̀ si, ṣùgbọ́n ọ̀nà kò fẹ̀ tó bi èrò àti ọkọ̀ ti pọ̀ tó, nitori eyi, sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ kò jẹ́ ki ará ilú gbádùn. Àwọn ti ó nlọ si ibi iṣẹ́ agogo mẹjọ ni lati kúrò ni ilé ki agogo marun tó lù, wọn yio si wọlé ni agogo mẹwa lẹhin ti wọn bá pari iṣẹ́ ni agogo marun. Ó kéré jù, òṣìṣẹ́ yio lo wákàtí mẹfa lati lọ àti bọ ni ibi iṣẹ́ nitori sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀. Ìjọba ko ti i ṣe ìpèsè omi ẹ̀rọ, ọ̀nà àdúgbò àti ohun amáyédẹrùn igbàlódé pàtàki ni àwọn agbègbè tuntun. Iná mọ̀nàmọ́ná ti dára di ẹ̀ si, nitori iná kò lọ púpọ̀ mọ́ bi ti tẹ́lẹ̀. Ni àwọn olú ilú ilẹ̀ Yorùbá yókù bi Ìbàdàn, Òṣogbo, Abẹ́òkúta, Àkúrẹ́ àti Adó-Èkìtì, kò si sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ bi ti Èkó ṣùgbọ́n iná mọ̀nàmọ́ná kò ṣe déédé bi ti ilú Èkó. Ọ̀wọ́n epo-ọkọ̀ ti ó gbòde ni igbà ọdún Kérésìmesì ti ó kọjá àti ni ibẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun ti lọ ṣùgbọ́n epo-ọkọ̀ wọn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé epo ni àwọn olú ilú yókù ju ti Èkó. Gbogbo ohun tita ló ti wọ́n si. Ó ṣòro lati lo ayélujára nitori ai ṣe déédé iná mọ̀nàmọ́ná àti ayélujára, pàtàki bi enia ba jade kúrò ni ilú Èkó, ṣùgbọ́n ó sàn ju ti àtẹ̀hin wá lọ. Ni àpapọ̀, ọyẹ́ jẹ́ ki ẹni ti ó bá nti Òkè-Òkun bọ̀ gbádùn nitori ooru din kù. “Ilú-Oyinbo dára, ọ̀rẹ́ mi òtútù pọ̀” Gẹgẹbi, àgbà ninu olórin Yorùbá “Délé Òjó” ti kọ ni ọpọlọpọ ọdún sẹhin pe “Ilú Oyinbo dára, ọrẹ mi òtútù pọ̀, à ti gbọmọ lọwọ èkùrọ́ o ki ma i ṣojú bọ̀rọ̀”. Àsikò òtútù ni àlejò ma ńṣe iranti ilé. Òtútù ò dára fún arúgbó, a fi ti onilé nã bá lówó lati san owó iná ti o gun òkè nitori àti tan ẹ̀rọ-amúlé gbónọ́. Ìmọ̀ràn fún àwọn ti ó gbé ìyá wọn wá si ìlú-oyinbo, ni ki wọn gbiyànjú lati ṣe ètò fún àwọn ìyá-àgbà lati lọ si ilé ni asiko òtútù lati fara mọ́ àwọn enia wọn. Òtútù o dára fún eegun àgbà. “A ki i fi ọjọ́ kan bọ́ ọmọ tó rù”: Ìmọ̀ràn fún Òṣèlú tuntun àti àwọn ará ilú Nigeria Ọmọ ki dédé rù lai ni idi. Lára àwọn idi ti ọmọ lè fi rù ni: àìsàn, ebi, òùngbẹ, ìṣẹ́, ai ni alabojuto, òbí olójú kòkòrò, ai ni òbí àti bẹ ẹ bẹ lọ. Orilẹ̀ èdè Nigeria ti jẹ gbogbo ìyà àwọn ohun ti ó lè mú ki ọmọ rù yi, lọ́wọ́ Ìjọba Ológun àti Òsèlú fún ọ̀pọ̀ ọdún. Nigbati àwọn òbí ti ó fẹ́ràn ọmọ bi Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àti àwọn àgbà ti ó bèrè fún Ominira lọwọ Ilú-Ọba, ṣe Òsèlú, ilú kò rù, pàtàki ọmọ Yorùbá. Wọn fi ọrọ̀ ajé àti iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ipinlẹ̀, pèsè ohun amáyédẹrùn fún ilú, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé-iwé ọ̀fẹ́, àwọn tó jade ni ilé-iwé giga ri iṣẹ́ gidi àti pé àwọn ará ilú tẹ̀ lé òfin. Eyi mú ìlọsíwájú bá ilẹ̀ Yorùbá ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú. Ilú bẹ̀rẹ̀ si rù lati igbà ti Ìjọba Ológun àkọ́kọ́ ti fi ipá kó gbogbo ipinlẹ̀ Nigeria si abẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ni ọdún mọ́kàndinlãdọta sẹhin . Lati igbà ti wọn ti kó ọrọ̀ ajé gbogbo ipinlẹ̀ si abẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ti a lè pè ni “Òbí” ti jinà si ará ilú ti a lè pè ni “Ọmọ” ti rù. Ojúkòkòrò àti olè ji jà Ìjọba Ológun àti Òṣèlú lábẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ti fa ebi, òùngbẹ àti àìsàn fún ará ilú. Ni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n sẹhin, Olóri Òsèlu tuntun Muhammadu Buhari àti àtẹ̀lé rẹ Túndé Ìdíàgbọn ṣe Ìjọba fún ogún oṣù gẹgẹ bi Ìjọba Ológun. Nigbati wọn gba Ìjọba lọ́wọ́ àwọn Òṣèlú ti ó ba ilú jẹ́ pẹ̀lú iwà ��bàjẹ́ ti wọn fi kó ilú si igbèsè lábẹ́ Olóri Òṣèlú Shehu Shagari, wọn fi ìkánjú ṣe idájọ́ fún àwọn tó hu iwà ibàjẹ́, eleyi jẹ ki ilú ké pé Ìjọba wọn ti le jù. Ká ni ilú farabalẹ̀ ni àsikò na a, ilú ki bá ti dára si. Nigbati Olóri-ogun Badamasi Babangida gba Ìjọba, inú ilú dùn nitori àyè gba ará ilú lati ṣe bi wọn ti fẹ lati ri owó. Eleyi jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ olówó ojiji pọ̀ si lati igbà na a titi di oni. Àyè àti ni owó ojiji nipa ifi owó epo-rọ̀bì ṣòfò, ki kó owó ìpèsè ohun amáyédẹrùn jẹ, gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti iwà ìbàjẹ́, ló pa ilé-iwé giga, ilé-ìwòsàn, pàtàki ìpèsè iná-mọ̀nàmọ́ná, ìdájọ́ àti bẹ ẹ bẹ lọ. A lè lo òwe “A ki i fi ọjọ́ kan bọ́ ọmọ tó rù” ṣe àlàyé pé iwà ìbàjẹ́ àti ohun tò bàjẹ́ fún ọdún pi pẹ́ kò ṣe tún ṣe ni ọjọ́ kan, nitori eyi, ki ará ilú ṣe sùúrù fún Ìjọba tuntun lati ṣe àtúnṣe lati ìbẹ̀rẹ̀. Ki Ìjọba tuntun na a mọ̀ pé “Ori bi bẹ́, kọ́ ni oògùn ori fi fọ́”, nitori eyi ki wọn tẹ̀ lé òfin lati ṣe ìdájọ́ fún àwọn ti ó ba ilú jẹ́. Ẹ Jọ̀wọ́ Darapọ̀ Mọ́ Wa lati kọ nipa Àṣà àti Ìtàn Àdáyébá ni Agbègbè Yin Gbogbo olólùfẹ́ èdè àti àṣà Yorùbá ti ó tẹ̀lé wa ni àwọn ọdún ti ó kọjá, a ki yin fún ọdún tuntun ti ó wọlé. Èdùmàrè á jẹ́ ki ọdún na a tura o. Inú wa yio dùn ti ẹ bá lè darapọ̀ mọ́ wa lati kọ nipa àṣà ati itàn àdáyébá ni agbègbè yin ni ilẹ̀ Yorùbá fún àkọọ́lẹ̀ ki èdè àti àṣà Yorùbá ma ba parẹ́. Èdè àti Àṣà Yorùbá kò ni parẹ́. Ìkini fún ọdún tuntun“A ki i jẹ Igún, a ki i fi Ìyẹ́ Igún rinti: Ẹnu Ayé Lẹbọ Ohun ti o jẹ èèwọ̀ tàbi òfin ni ilú kan le ma jẹ èèwọ̀/òfin ni ilú miran ṣùgbọ́n bi èniyàn bá dé ilú, ó yẹ ki ó bọ̀wọ̀ fún àṣà àti òfin ilú. Bi èniyàn bá ṣe nkan èèwọ̀, ó lè ṣé gbé ti kò bá si ẹlẹri lati ṣe àkóbá tàbi ki ó fi ẹnu ṣe àkóbá fún ara rẹ̀. Ni ilú kan ti a mọ̀ si “Ayégbẹgẹ́”, àwọn àlejò ọkùnrin meji kan wa ti orúkọ wọn njẹ́ – Miòṣé àti Moṣétán. Ọba ilú Ayégbẹgẹ́ kede pé èèwọ̀ ni lati jẹ ẹiyẹ Igún ni ilú wọn. Akéde ṣe ikilọ̀ pé ẹni ti ó bá jẹ Igún, ikùn rẹ yio wu titi yio fi kú ni. Àwọn àlejò meji yi ṣe ìlérí pé kò si nkan ti yio ṣẹlẹ̀ ti àwon bá jẹ Igún, nitori eyi wọn fi ojú di èèwọ̀ ilú Ayégbẹgẹ́. Miòṣé, lọ si oko, ó pa Igun, ó din láta, ó si jẹ́, ṣùgbọ́n ó pa adiẹ, ó da iyẹ́ adiẹ si ààtàn bi ẹni pé adiẹ ló jẹ. Ọ̀pọ̀ ará ilú ti wọn mọ̀ pé èèwọ̀ ni lati jẹ Igún paapa, jẹ ninú rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò mọ pé Igún ni àwọn jẹ, wọn rò wi pé adiẹ ni. Miòṣé fi ọ̀rọ̀ àṣiri yi sinú lai si nkan ti ó ṣe gbogbo àwọn ti ó jẹ Igún pẹ̀lú rẹ. Moṣétán lọ si oko ohun na a pa Igun, ó gbe wá si ilé, ṣùgbọ́n kò jẹ́. Ó pa adiẹ dipò Igún, o din adiẹ ó jẹ ẹ, ṣùgbọ́n, ó da iyẹ́ Igún si ààtàn bi ẹni pé Igún lohun jẹ. Ni ọjọ́ keji àwọn ará ilú ri iyẹ́ Igún wọn pariwo pé Moṣétán jẹ èèwọ̀, ó ni bẹni, ohun jẹ Igún. Ni ọjọ́ kẹta inú Moṣétán bẹ̀rẹ̀ si i wú titi ara fi ni. Nigbati ìnira pọ̀ fún Moṣétán, ó jẹ́wọ́ wi pé adiẹ lohun jẹ, ṣùgbọ́n wọn ko gba a gbọ pé kò jẹ Igun, titi ti ó fi ṣubú ti ó si kú. Yorùbá ni “Ẹnu Ayé Lẹbo”, Moṣétán fi ẹnu kó bá ara rẹ̀. Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pé, àfojúdi kò dára, ó yẹ ki enia pa òfin mọ nitori “Bi a ti nṣe ni ilé wa, èèwọ̀ ibò miran”. Ẹni ti kò bá pa òfin mọ, á wọ ijọ̀ngbọ̀n ti ó lè fa ikú tàbi ẹ̀wọ̀n. “Ṣe bi o ti mọ ki i tẹ́ – Ọdún wọlé dé” Ọdún Kérésì jẹ́ ọdún Onigbàgbọ́ lati ṣe iránti ọjọ́ ibi Jésù Olùgbàlà. Ọjọ́ kẹjọ lẹhin ọdún Kérésìmesì ni ọdún tuntun. Fún ayẹyẹ ọdún, kò si iyàtọ̀ laarin Ìgbàgbọ́ àti Mùsùlùmi ni ilẹ̀ Yorùbá nitori Yorùbá gbà wi pé “Ẹni ọdún bá láyé, ó yẹ kó dúpẹ́”. Ọpẹ́ ló yẹ ki èniyàn dá ju igbèsè ji jẹ lati ṣe àṣe hàn ni àsikò ọdún. Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, àwọn Àgbẹ̀ á dari wálé pẹ̀lú irè oko pàtàki iṣu. Àwọn Oniṣòwò á ri ọjà tà nitori àsikò yi ni Bàbá àti Ìyá ma nrán aṣọ ọdún fún àwọn ọmọdé àti oúnjẹ rẹpẹtẹ fún ipalẹ̀mọ́ ọdún. Inú ọmọdé ma ndùn nitori asiko yi ni wọn nse irẹsi àti pa adiẹ fún ọdún. Àwọn ọmọdé á lọ lati ilé ẹbi kan si ekeji, ẹbi ti wọn lọ ki, á fún wọn ni oúnjẹ àti owó ọdún. Àwọn àgbàlagbà naa ma ndá aṣọ ẹgbẹ́ fún idúpẹ́ ọdún, ṣùgbọ́n ki owó epo rọ̀bi tó gba igboro, ki ṣe aṣọ olówó nla bi ti ayé òde òni. Àsikò ti olè npọ̀ si niyi pàtàki ni ilú Èkó, nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ fẹ na owó ti wọn kò ni lati ṣe ọdún. Ìpolówó ọjà pọ̀ ni àsikò yi ni Òkè-Òkun, nitori eyi, ọ̀pọ̀ nlo ike-igbèsè tàbi ki wọn ya owó-èlè lati ra ọjà ti wọn kò ni owó rẹ. Lẹhin ọdún, wọn a fi ọdún tuntun bẹ̀rẹ̀ si san igbèsè, nitori eyi Ìyá àti Bàbá a ma a ti ibi iṣẹ́ kan lọ si ekeji lai ni ìsimi tàbi ri àyè àti bójú tó àwọn ọmọ. Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ wi pé “Ṣe bi o ti mọ ki i tẹ́ ”, nitori eyi gbogbo ọmọ Yorùbá ni ilé, ni oko, ẹ ṣe bi ẹ ti mọ, ẹ ma tori odun na ọwọ́ si nkan ti ọwọ́ yin kò tó, ki ẹ ma ba a tẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Onigbàgbọ́ ayé òde oni ki i fẹ fi èdè Yorùbá kọrin ṣùgbọ́n ẹ gbọ́ bi ọmọ Òyinbó ti kọ orin àwọn “Obinrin Rere” ni ojú iwé yi. Èkó – Aginjù laarin àwọn Olú Ilú Àgbáyé Èkó ni olú ilú Nigeria fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ki àwọn Ijọba Ológun tó kó Olú Ilú Nigeria lọ si Abuja ni bi ọdún mẹrinlélógún sẹhin. Ki kó olú ilú kúrò ni Èkó kò din èrò ti o nwọ Èkó kù, ilú Èkó ngbòrò si ni, ṣùgbọn bi èrò ti npọ si, Ijọba àpapọ̀ kò ran Eko lọwọ nipa ipèsè owó tó tó ni àsikò fún ohun amáyédẹrùn. Ká fi Èkó wé àwọn olú ilú yoku ni àgbáyé àti àwọn ilú nla ti omi yi ká, inira Èkó pọ̀ ju àwọn ilú wọnyi lọ. Kò si iná mọ̀nàmọ́ná ti ó ṣe deede, kò si omi mimu fún ará ilú pàtàki fún àwọn agbègbè titun. Eyi ti ó burú jù ni ki èniyàn jade, kó má mọ igbà ti ó ma padà wọlé nipa li lo bi wákàti mẹ́fà tàbi ju bẹ́ ẹ̀ lọ ninú sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ ọkọ̀, nitori ọ̀nà kò tó, bẹni kò dára, iwà-kuwà pọ̀ fún awakọ̀, ọkọ̀ àti èrò pọ̀ ju òpópó ọ̀nà lọ. Bi Ijọba àpapọ̀ Nigeria ti ri owó ori gbà ni Èkó ju gbogbo àwọn ilú yoku lọ tó, kò si irànlọ́wọ́ lati tú ọ̀nà Ijọba àpapọ̀ ṣe. Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, Ijọba Ológun di Èkó lọ́wọ́ lati pèsè ọkọ̀ ojú irin ti ó ngbé èrò púpọ̀ ti Gómìnà Lateef Jakande bẹ̀rẹ̀. Bi Èkó ti tóbi tó, ibùdókọ òfúrufú kan ló wà lójú kan naa ni Ìkẹjà fún àwọn ti ó nlọ si gbogbo àgbáyé àti àwọn ti ó fẹ́ lọ si ilú Nigeria miran. Lati igbà ti Ijọba Ológun ti lé àwọn àjòjì ti ó dá ilé ọjà nla silẹ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwọn Olówó ilú kò ronú lati ṣe irú ilé ọjà bẹ́ ẹ̀ si gbogbo agbègbè Èkó fún irọ̀rùn ará ilú ju bi gbogbo ọjà nla ti kó ori jọ si Erékùṣù Èkó. Àwọn nkan wọnyi àti iwà ibàjẹ́ àti ojúkòkòrò Ijọba Ológun àti Alágbádá (Òṣèlú) ló sọ Èkó di aginjù laarin àwọn olú ilú àgbáyé. A lérò wi pé Ijọba Òṣèlú ti àwọn ará ilú yàn fún “àyipadà” kúrò ninú iwà ibàjẹ́ tó gba orilẹ̀ èdè kan fún igbà pi pẹ́, yio wa àtúnṣe fún Èkó. Gómìnà Akinwunmi Àmbọ̀dé ni lati wá àtúnṣe si iyà ti ojú ará ilú nri nipa gbi gbé ọkàn lé ọkọ̀ ilẹ́ fún ohun irinna nikan, nipa pi pari iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin àti ibùdókọ̀ ojú omi ti Ijọba Gómìnà Babátúndé Raji Fáṣọlá bẹ̀rẹ̀, ki wọn si ṣe kun nipa ipèsè ibùdókọ òfúrufú àti ohun amáyédẹrùn yoku. Èkó kò ni bàjẹ́ o – ó bàjẹ́ ti. Ọbẹ̀ tó dùn, Owó ló pá: Àwòrán àti pi pè Èlò Ọbẹ̀ Òwe Yorùbá ni “Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pá”, ṣùgbọ́n kò ri bẹ̃ fún ẹni ti kò mọ ọbẹ̀ se. Elomiran lè lo ọ̀kẹ́ àimọye owó lati fi se ọbẹ̀ kó má dùn nitori, bi iyọ̀ ò ja, ata á pọ̀jù tàbi ki omi pọ̀jù. Ni tõtọ, owó ni enia ma fi lọ ra èlò ọbẹ̀ lọ́jà, ṣùgbọ́n fún ẹni ti ó mọ ọbẹ̀ se, ìwọ̀nba owó ti ó bá mú lọ si ọjà, ó lè fi ra èlò ọbẹ̀ gẹ́gẹ́ bi owó rẹ ti mọ, ki ó si se ọbẹ̀ na kó dùn. Ẹ wo àwòrán àti pipè èlò ọbẹ ni abala ojú iwé yi. Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú Awólọ́wọ̀, Iyalode Rẹ́mọ, Yèyé Oòduà relé pẹ̀lú ijó àti ayọ̀ A bi Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú ni ọjọ́ karundinlọ́gbọ̀n, oṣù kọkanla, ọdún Ẹ̀dẹ́ẹ́gbãlemẹ̃dógún, ó ṣe igbéyàwó pẹ̀lú Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àgbà Òṣèlú ni ọjọ́ kẹrindinlọ́gbọ̀n, oṣù kejila, Ẹ̀dẹ́ẹ́gbãlemẹ̃tadinlọ́gbọ̀n, o jade láyé nigbati ó kú bi oṣú meji ó lé di ẹ ki ó pé ọgọrun ọdún. “Lẹhin ọkùnrin tàbi obinrin (ni ayé òde òni) ti ó bá ṣe ori-ire, obinrin tàbi ọkunrin rere wa lẹhin tabi ẹ̀gbẹ rẹ”. Òwe yi ni a lè fi ṣe àpẹrẹ iṣẹ́ ribiribi ti Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú ṣe fún Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, ògúná gbongbo Òṣèlú ni ilẹ̀ Yorùbá àti fún orilẹ̀ èdè Nigeria. Nigbati Bàbá mba iṣẹ́ oselu kiri gbogbo àgbáyé, Iyá ló di ilé mú, ti ọkàn Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ fi balẹ̀ lati le fi ipò Olóri Òsèlú ṣe iṣẹ́ ribiribi ti ó ṣe. Titi di ọjọ́ ikú ọkọ rẹ ni ọdún mejidinlọ́gbọ̀n sẹhin, lẹhin igbéyàwó àádọ́ta ọdún, ó ṣe àti lẹhin fún ọkọ rẹ titi di ọjọ́ alẹ́, eyi jẹ àpẹrẹ rere fún gbogbo obinrin. Ẹbi àti ará ti bẹ̀rẹ̀ si palẹ̀mọ́ fún ọjọ́ ibi ọgọrun fún Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú nigbati iròyin ikú rẹ jade pé iyá sùn ni ọjọ kọkàndinlógún, oṣú kẹsan ọdún Ẹgbàálemẹ̃dógún. Ipalẹ̀mọ́ ìsìnku bẹ̀rẹ lati ṣe àṣeyẹ ikẹhin fún olóògbé dipò ayẹyẹ ọjọ́ ọgọrun ibi. Olóri Òṣèlú Nigeria Muhammadu Buhari pẹ̀lú àwọn àgbà Òsèlú, àwọn Ọba àti Ìjòyè, ọmọdé àti àgbà ilú dara pọ̀ pẹ̀lú ẹbi àti àwọn ọmọ Olóògbé lati ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin fún Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú Awólọ́wọ̀ ni ọjọ́ karùndinlọ́gbọ̀n, oṣù kọkanla ọdún Ẹgbàálemẹ̃dógún. Sùn re o, ó digbà, o di gbóṣe. Ọba titun, Ọọni Ifẹ̀ Kọkànlélaadọta gba Adé Ilé-Ifẹ̀ tàbi Ifẹ̀ jẹ ilú àtijọ́ ti Yorùbá kà si orisun Yorùbá. Lẹhin ọjọ mọ́kànlélógún ni Ilofi (Ilé Oyè) nigbati gbogbo ètùtù ti ó yẹ ki Ọba ṣe pari, Ọba Adéyẹyè Ẹniitàn, Ògúnwùsi gba Adé Aàrẹ Oduduwa ni ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kọkànlá ọdún Ẹgbàálemẹ͂dógún ni Òkè Ọra nibiti Bàbá Nlá Yorùbá Oduduwa ti kọ́kọ́ gba adé yi ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin. Ọba Ogunwusi, Ọjaja Keji, di Ọba kọkànlélaadọta Ilé Ifẹ̀, lẹhin ti Ọba Okùnadé Sijúwadé pa ipò dà ni ọjọ́ kejidinlọgbọn, oṣù keje odun Ẹgbàálemẹ͂dógún. Gẹ́gẹ́ bi àṣà àdáyébá, ẹ͂kan ni ọdún nigba ọdún Ọlọ́jọ́ ti wọn ma nṣe ni oṣù kẹwa ọdún ni Ọba lè dé Adé Aàrẹ Oduduwa. Adé á pẹ́ lóri o, bàtà á pẹ́ lẹ́sẹ̀. Igbà Ọba Adéyẹyè Ẹniitàn, Ògúnwùsi á tu ilú lára. lè dé Adé Àrẹ Oduduwa. Bi a bá tori ẹni burúkú fọ́jú, a kò ni ri ojú ri ẹni rere Kò si ilú, ẹ̀yà tàbi àwọ̀ ti kò ni ẹni burúkú tàbi ẹni rere. Àti ẹni burúkú àti ẹni rere ló wà ninú ẹbi, ilú, àti gbogbo ẹ̀yà àgbáyé ninú èniyàn dúdú àti funfun, ọkùnrin, obinrin, ọmọdé àti àgbà. Bi èniyàn bá pàdé ẹni kan tàbi meji ni àkọ́kọ́, ti ó ti ẹ̀yà tàbi ilú kan jade, ti ó si hùwà rere, ni ọ̀pọ̀ igbà, ó wọ́pọ̀ lati rò wi pé gbogbo ará ilú bẹ́ ẹ̀ ló dára, ni ida keji, ti irú ẹni bẹ́ ẹ̀ ba hùwà burúkú, ó wọ́pọ̀ lati rò wi pé gbogbo ẹni ti ó ti irú ẹ̀yà yi jade ni ẹni burúkú. Ọ̀pọ̀ igbà, lai pàdé enia ri, ẹlòmiràn lè ni lọ́kàn pe ẹni burúkú tàbi ẹni rere ni ohun pàdé nitori itàn ti ó ti gbọ́. Itàn yi lè nipá lóri irú iwà ti èniyàn yio hu si ẹni ti a bá pàdé. Fún àpẹrẹ, wọn a ni Ìjẹ̀bú fẹ́ràn owó ju ẹmi lọ, Ondó njẹ Ajá, Ọ̀yọ́ ‘ayọ́mọọ́lẹ̀’’, Èkìtì ni agidi, Ìjẹ̀shà – Òṣómàáló’ àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ. Ki ṣe gbogbo àwọn ará ilú wọnyi ló bá àpèjúwe yi mu. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fọ́jú nitori iwà burúkú ẹni kan tàbi itàn burúkú. Ó wọ́pọ̀ laarin ẹbi ọkùnrin àti obinrin àfẹ́sọ́nà, ki obi kọ̀ ki wọn fẹ́ra nitori itàn pé idilé tàbi ilú ti ikan ninú ọkùnrin tàbi obinrin ti jade kò dára. Lára ewu ti ó wà ninú ki èniyàn tori ẹni burúkú fọ́jú, ọ̀pọ̀ ti tàsé iyàwó tàbi ọkọ rere lai farabalẹ̀ wo iwà ẹni ti ọmọ wọn mú wálé tàbi tàsé ẹni rere. Nitori òwe Yorùbá ti ó sọ pé “Bi a bá tori Ẹni burúkú fọ́jú, a kò ni ri ojú ri ẹni rere”, ó yẹ ki a farabalẹ̀ wo iwà ẹni ti a bá pàdé ju ki itàn tàbi iwà awọn diẹ ba gbogbo ẹni ti ó bá ti ẹbi, ilú tàbi ẹ̀yà kan jẹ́, ki á lè ri ojú ri ẹni rere. Ẹni tó ni Ẹrú ló ni Ẹrù – Ìtàn Bàbá tó kó gbogbo ogún fun Ẹrú Ni ayé igbà kan ri ki ṣe oye ọkọ, ilé gogoro, aṣọ àti owó ni ilé-ìfowó-pamọ́ ni a fi nmọ Ọlọ́rọ̀ bi kò ṣe pé oye Ẹrú, Ìyàwó, Ọmọ, Ẹran ọsin àti oko rẹpẹtẹ ni a fi n mọ Ọlọ́rọ̀. Ni àsikò yi, Bàbá kan wa ti ó ni Iyawo púpọ̀, Oko rẹpẹtẹ, ogún-lọ́gọ̀ ohun ọsin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ẹrú tàbi Alágbàṣe, Ọmọ púpọ̀, ṣùgbọ́n ninú gbogbo ọmọ wọnyi, ikan ṣoṣo ni ọkùnrin. Bàbá fi ikan ninú gbogbo Ẹrú ti ó ti pẹ́ pẹ̀lú rẹ, ṣe Olóri fún àwọn Ẹrú yoku. Ẹrú yi fẹ́ràn Bàbá, ó si fi tọkàn-tọkàn ṣe iṣẹ́ fún. Nigbati Bàbá ti dàgbà, ó pe àwọn àgbà ẹbí lati sọ àsọtẹ́lẹ̀ bi wọn ṣe ma a pín ogún ohun lẹhin ti ohun bá kú nitori kò si iwé-ogún bi ti ayé òde oni. Ó ṣe àlàyé pé, ohun fẹ́ràn Olóri Ẹrú gidigidi nitori o fi tọkàn-tọkàn sin ohun, nitori na a, ki wọn kó gbogbo ohun ini ohun fún Ẹrú yi. Ó ni ohun kan ṣoṣo ni ọmọ ọkùnrin ohun ni ẹ̀tọ́ si lati mu. Lẹhin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, Bàbá re ibi àgbà nrè, ó ku. Lẹhin ìsìnkú, àwọn ẹbí àti àwọn ọmọ Olóògbé pé jọ lati pín ogún. Ni àsikò yi, ọmọ ọkùnrin ni ó n jogún Bàbá, pàtàki àkọ́bí ọkùnrin nitori ohun ni Àrólé. Gẹgẹ bi àsọtẹ́lẹ̀, wọn pe Olóri Ẹrú jade, wọn si ko gbogbo ohun ini Bàbá ti o di Oloogbe fún. Wọn tún pe ọmọ ọkùnrin kan ṣoṣo ti Bàbá bi jade pé ó ni ẹ̀tọ́ lati mu ohun kan ti ó bá wu u ninú gbogbo ohun ini Bàbá rẹ, nitori eyi wọn fún ni ọjọ́ meje lati ronú ohun ti ó bá wù ú jù. Àwọn ẹbí sun ìpàdé si ọjọ́ keje. Inú Ẹrú dùn púpọ̀ nigbati inú ọmọ Bàbá bàjẹ́. Eyi ya gbogbo àwọn ti ó pé jọ lẹ́nu pàtàki ọmọ Bàbá nitori ó rò pé Bàbá kò fẹ́ràn ohun. Lẹhin ìbànújẹ́ yi, ó gbáradi, ó tọ àwọn àgbà lọ fún ìmọ̀ràn. Ni ọjọ́ keje, ẹbí àti ará tún péjọ lati pari ọ̀rọ̀ ogún pin-pin, wọn pe ọmọ Bàbá jade pé ki ó wá mú ohun kan ṣoṣo ti ó fẹ́ ninú ẹrù Baba rẹ. Ó dide, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ti ó joko, ó yan Olóri Ẹrú gẹgẹ bi àwọn àgbà ti gba a ni ìyànjú. Inú Ẹrú bàjẹ́, ṣùgbọ́n o ni ki Ẹrú má bẹ̀rù, Ẹrú na a ṣe ìlérí lati fi tọkàn-tọkàn tọ́jú ohun ti Bàbá fi silẹ̀. Idi niyi ti Yorùbá ṣe ma npa a lowe pe “Ẹni tó ni Ẹrú ló ni Ẹrù.” Lára ẹ̀kọ́ itàn yi ni pé, ó dára lati lo ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n nitori “Ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n ni ki i jẹ ki á pe àgbà ni wèrè”. Ẹ̀kọ́ keji ni pé, ogún ti ó ṣe pàtàki jù ni ki á kọ ọmọ ni ẹ̀kọ́ lati ilé àti lati bójú tó ẹ̀kọ́ ilé-iwé. Bi ọmọ ò jọ ṣòkòtò á jọ kíjìpá: Ibáṣe pọ Idilé Yorùbá Bàbá, iyá àti ọmọ ni wọn mọ si Idilé ni Òkè-òkun ṣùgbọ́n ni ilẹ̀ Yorùbá kò ri bẹ́ ẹ̀, nitori ẹbi Eg bàbá, ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ẹni, ọmọ, ọkọ àti aya wọn ni a mọ̀ si Idilé. Yorùbá fẹ́ràn lati má a bọ̀wọ̀ fún àgbà nitori eyi, ẹni ti ó bá ju Bàbá àti Ìyá ẹni lọ Bàbá tàbi Ìyá la n pè é, wọn ki pe àgbà ni orúko nitori eyi, wọn lè fi orúkọ ọmọ pe àgbà tàbi ki wọn lo orúkọ apejuwe (bi Bàbá Èkó, Iyá Ìbàdàn). Ẹ ṣe à yẹ̀ wò àlàyé àti pi pè ibáṣepọ̀ idilé ni ojú iwé yi. Bi Ọdẹ bá ro ìṣẹ́ ro ìyà inú igbó, ti ó bá pa ẹran kòní fẹ́nì kan jẹ Láyé àtijọ́, iṣẹ́ Ọdẹ jẹ ikan ninú iṣẹ gidi ni ile Yorùbá. Ògbójú Ọdẹ ló npa ẹranko bi Erin, Ẹkùn, Kìnìún àti Ẹfòn, Ìmàdò, Ikõkò, nígbàtí àwọn to nṣe Ọdẹ etílé npa ẹranko ìtòsí ilé bi Ọ̀kẹ́rẹ́, Òkété, Ọ̀bọ àti bẹ̃bẹ lọ. Ẹran ìgbẹ bi Ìgalà, Àgbọ̀nrín àti , ẹran ọ̀sìn bi Àgùntàn, Ewurẹ, Òbúkọ, Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ ẹran tí o wọ́pọ̀ fún jíjẹ ni ayé àtijọ dípò ẹran Mãlu tí ó wá wọpọ láyé òde òní. Àwọn ẹranko bi Ẹfọ̀n, Erin, Kìnìún, Ẹkùn ti dínkù nígbàtí ẹranko bi Àgbánreré ti parẹ́ ni ilẹ̀ Yorùbá. A lè fi ò̀we Yorùbá “Bi Ọdẹ bá ro ìṣẹ́ ro ìyà inú igbó, ti ó bá pa ẹran kòní fẹ́nì kan jẹ” wé ìyá ti àwọn ti ó wà ni Ìlúọba/Ò̀kèòkun njẹ nínú òtútù lati pa owó. Nínú owó yi, wọn a ronú àti ran àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ti wọn gbìyànjú lati ràn lọ́wọ́, ki i wo ìya ti ojú wọn rí. Ẹ rántí wípé ẹni ti o bá laanu ló lè ronú lati ran ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ìtàn bi Ìjàpá ti fa Àkóbá fún Ọ̀bọ: Ẹ Ṣọ́ra fún Ọ̀rẹ́ Burúkú Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ itàn Yorùbá, Ìjàpá jẹ ọ̀lẹ, òbùrẹ́wà, kò tóbi tó àwọn ẹranko yoku, ṣùgbọ́n ó ni ọgbọ́n àrékérekè ti ó fi ngbé ilé ayé. Ò̀we Yorùbá sọ wi pé, “Iwà jọ iwà, ni ọ̀rẹ́ jọ ọ̀rẹ́”, ṣùgbọ́n ninú itàn yi, iwà Ìjàpá àti Ọ̀bọ kò jọra. Ìjàpá pẹ̀lú Ọ̀bọ di ọ̀rẹ́ nitori wọn jọ ngbé àdúgbò. Gbogbo ẹranko yoku mọ̀ wi pé iwà wọn kò jọra nitori eyi, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wọn irú ọ̀rẹ́ ti wọn bára ṣe. Ọgbọ́n burúkú kó wọn Ìjàpá, ni ọjọ́ kan ó bẹ̀rẹ̀ si ṣe àdúrà lojiji pé “Àkóbá , àdábá, Ọlọrun ma jẹ ká ri”, Ọ̀bọ kò ṣe “Àmin àdúrà” nitori ó mọ̀ wi pé kò si ẹni ti ó lè ṣe àkóbá fún Ìjàpá, à fi ti ó bá ṣe àkóbá fún elòmiràn. Inú bi Ìjàpá, ó ka iwà Ọ̀bọ yi si à ri fin, ó pinu lati kọ lọ́gbọ́n pé ọgbọ́n wa ninú ki enia mã ṣe “Àmin” si àdúrà àwọn àgbà. Ìjàpá ṣe àkàrà ti ó fi oyin din, o di sinú ewé, ó gbe tọ Ẹkùn lọ. Ki Ẹkùn tó bèrè ohun ti Ìjàpá nwa lo ti gbo oorun didun ohun ti Ìjàpá Ijapa gbe wa. Ìjàpá jẹ́ ki Ẹkùn játọ́ titi kó tó fún ni àkàrà olóyin jẹ. Àkàrà olóyin dùn mọ́ Ẹkùn, ó ṣe iwadi bi òhun ti lè tún ri irú rẹ. Ìjàpá ni àṣiri ni pé Ọ̀bọ ma nṣu di dùn, lára igbẹ́ rẹ ni òhun bù wá fún Ẹkùn. Ó ni ki Ẹkùn fi ọgbọ́n tan Ọ̀bọ, ki ó si gba ni ikùn diẹ ki ó lè ṣu igbẹ́ aládùn fun. Ẹkùn kò kọ́kọ́ gbàgbọ́, ó ni ọjọ́ ti òhun ti njẹ ẹran oriṣiriṣi, kò si ẹranko ti inú rẹ dùn bi eyi ti Ìjàpá gbé wá. Ìjàpá ni ọ̀rẹ òhun kò fẹ́ ki ẹni kan mọ àṣiri yi. Ẹkùn gbàgbọ́, nitori ó mọ̀ wi pé ọ̀rẹ́ gidi ni Ìjàpá àti Ọ̀bọ. Ẹkùn lúgọ de Ọ̀bọ, ó fi ọgbọ́n tan ki ó lè sún mọ́ òhun. Gẹ́rẹ́ ti Ọ̀bọ sún mọ́ Ẹkùn, o fã lati gba ikùn rẹ gẹ́gẹ́ bi Ìjàpá ti sọ, ki ó lè ṣu di dùn fún òhun. Ó gbá ikun Ọ̀bọ titi ó fi ya igbẹ́ gbi gbóná ki ó tó tu silẹ̀. Gẹ́rẹ́ ti Ẹkùn tu Ọ̀bọ silẹ̀, ó lo agbára diẹ ti ó kù lati sáré gun ori igi lọ lati gba ara lowo iku ojiji. Ẹkùn tọ́ igbẹ́ Ọ̀bọ wò, inú rẹ bàjẹ́, ojú ti i pé òhun gba ọ̀rọ̀ Ìjàpá gbọ. Lai pẹ, Ìjàpá ni Ọ̀bọ kọ́kọ́ ri, ó ṣe àlàyé fún ọ̀rẹ́ rẹ ohun ti ojú rẹ ri lọ́wọ́ Ẹkùn lai funra pé Ìjàpá ló fa àkóbá yi fún òhun. Ìjàpá ṣe ojú àánú, ṣùgbọ́n ó padà ṣe àdúrà ti ó gbà ni ọjọ́ ti Obo kò ṣe “Amin”, pé ọgbọ́n wà ninú ki èniyàn mã ṣe “Àmin” si àdúrà àwọn àgbà. Kia ni Ọ̀bọ bẹ̀rẹ̀ si ṣe “Àmin” lai dúró. Idi ni yi ti Ọ̀bọ fi bẹ̀rẹ̀ si kólòlò ti ó ndún bi “Àmin” titi di ọjọ́ òni. Ẹ̀kọ́ itàn yi ni pé, bi èniyàn bá mbá ọ̀rẹ́ ọlọ́gbọ́n burúkú rin, ki ó mã funra tàbi ki ó yẹra, ki o ma ba ri àkóbá. Ránti Ọmọ Ẹni ti Iwọ Nṣe: Olè ki ṣe Orúkọ Rere lati fi Jogún Oriṣiriṣi òwe ni Yorùbá ni lati fihàn pé iwà rere ló ni ayé. Iwà ni Yorùbá kàsí ni ayé àtijọ́ ju owó ti gbogbo ilú bẹ̀rẹ̀ si bọ ni ayé òde òni. Fún àpẹrẹ, Yorùbá ni “Ẹni bá jalè ló bọmọ jẹ́”, lati gba òṣiṣẹ́ ni ìyànjú pé ki wọn tẹpámọ́ṣẹ́, ki wọn má jalè. Ni ayé òde òni, owó ti dipò iwà. Olóri Ijọ, Olóri ilú àti Òṣèlú ti ó ja Ijọ àti ilú ni olè ni ará ilú bẹ̀rẹ̀ si i bọ ju àwọn Olóri ti kò lo ipò lati kó owó ijọ àti ilú fún ara wọn. Owó ti ó yẹ ki Olóri Ijọ fi tọ́jú aláìní, tàbi ki Òṣèlú fi pèsè ohun amáyédẹrùn bi omi mimu, ọ̀nà tó dára, ilé ìwòsàn, ilé-iwé, iná mọ̀nàmọ́ná àti bẹ ẹ bẹ ẹ lọ ni wọn kó si àpò, ti wọn nná èérún rẹ fún ijọ tàbi ará ilú ti ó bá sún mọ́ wọn. Ará ilú ki ronú wi pé “Alaaru tó njẹ́ búrẹ́dì, awọ ori ẹ̀ ló njẹ ti kò mọ̀”. Owé Yorùbá ti ó sọ wi pé “Ránti ọmọ Ẹni ti iwọ nṣe ” pin si ọ̀nà méji. Ni apá kan, inú ọmọ ẹni ti ó hu iwà rere ni àwùjọ á dùn lati ránti ọmọ ẹni ti ó nṣe, ṣùgbọ́n inú ọmọ “Olè”, apànìyàn, àjẹ́, àti oniwà burúkú yoku, kò lè dùn lati ránti ọmọ ẹni ti wọn nṣe. Nitori eyi, ki èniyàn hu iwà rere. Ijẹbu lo ni Ìfọ́kọrẹ́/Ìkọ́kọrẹ́ gbogbo Yorùbá ló ni Ọ̀jọ̀jọ̀ Ẹ ṣe àyẹ̀wò bi a ti ńṣe Ọ̀jọ̀jọ̀ lójú iwé yi. Fọ Iṣu Ewùrà kan Bẹ ewùrà yi Rin iṣu yi (pẹ̀lú pãnu ti a dálu lati fi rin gãri, ilá tàbi ewùrà) Po iyọ̀ àti iyọ̀ igbàlódé, ata gigún tàbi rẹ́ atarodo tútù, rin tàbi rẹ àlùbọ́sà si ewùrà rí-rin yi Ti ó ba ki, fi omi diẹ si lati po gbogbo ẹ pọ Gbe epo tàbi òróró kaná, Bi ó bá ti gbóná, a lè fi ṣibi tàbi ọwọ́ da ewùrà ri-rin ti a ti pò pẹ̀lú èlò́ yi si inú epo to gbóná lati din Wa kuro bi o ba ti jina. Ìbà Àkọ́dá, ìbà Aṣẹ̀dá Ìbà ni n ó f’òní jú, mo r’íbà, k’íbà ṣẹ Nínú ríríjẹ, nínú àìríjẹ Mo wá gbégbá ọpẹ́, mo r’íbà k’íbà ṣẹ Alápáńlá tó so’lé ayé ró Ṣe àtúntò ayé mi Ní gbogbo ọ̀nà tí mo ti k’etí ikún sí Ọ Baba d’áríjì, mo bẹ̀bẹ̀ Odò Orisun Rẹ ni mí, máṣe jẹ́ n gbẹ Ìbà! ìbà!! Ọmọ ìkà ń d’àgbà, ọmọ ìkà ń gbèrú Ọmọ ẹni ire a má a tọrọ jẹ Ọmọ onínúure a má a pọ́njú Bó ti wù Ọ ́lo ń ṣ’ọlá Rẹ Ìṣe Rẹ, Ìwọ ló yé o; Ògo Rẹ, é dibàjẹ́ Àpáta ayérayé, mo sá di Ọ ́o Yọ́yọ́ l’ẹnu ayé Aráyé ń sọ Ọ ́sí láburú, aráyé ń sọ Ọ ́sí rere Ọlọ́jọ́ ń ka’jọ́ Bó pẹ́, bó yá, ohun ayé á b’áyé lọ Ìbà! ìbà!! Ẹni iná ọ̀rẹ́ bá jó rí, bó bá ní’hun nínú kò ní lè rò ọ̀rẹ́ gidi ń bẹ bíi ká f’ẹ́ni dé’nú ọ̀rẹ́ ló ṣe’ni l’ọ́ṣẹ́ tó ku s’ára bí iṣu Ìrètí nínú ènìyàn, irọ́ funfun gbáláhú! ọ̀rẹ́ kan tí mo ní Elédùmarè, Alágbára, ìbà Rẹ o Baba, Atóbijù! Ìbà! ìbà!! “Obinrin ki ṣe Ẹrú tabi Ẹrù ti wọn njẹ mọ́ Ogún – Àsikò tó lati Dáwọ́ Àṣà ṣì Ṣúpó Dúró” Ni ayé àtijọ́, àṣà ṣì ṣúpó wọ́pọ̀ ni Ilẹ̀ Yorùbá. Obinrin ti ọkọ rẹ̀ bá kú wọn yio fi jogún gẹ́gẹ́ bi iyàwó fún ọmọ ọkọ ọkùnrin tàbi ẹbi ọkọ ọkùnrin. Eleyi wọ́pọ̀, pàtàki ni idilé Ọba, Ìjòyè nla, Ọlọ́rọ̀ ni àwùjọ àti àgbàlagbà ti ó fẹ́ iyàwó púpọ̀. Bi Ọba bá wàjà, Ọba titun yio ṣu gbogbo iyàwó ti ó bá láàfin lópó. Ni ayé ọ̀làjú ti òde òni, àṣà ṣì ṣúpó ti din kù púpọ̀, nitori ẹ̀sìn àti àwọn obinrin ti ó kàwé ti ó si ni iṣẹ́ lọ́wọ́ kò ni gbà ki wọn ṣú ohun lópó fún ẹbi ọkọ ti kò ni ìfẹ́ si. Ọkùnrin ni ẹbi ọkọ na a ti bẹ̀rẹ̀ si kọ àṣà ṣì ṣúpó silẹ̀ pàtàki àwọn ti ó bá kàwé, nitori ó ti lè ni iyàwó tàbi ki ó ni àfẹ́sọ́nà. Lai ti ẹ ni iyàwó, ọkùnrin ẹbi ọkọ lè ma ni ìfẹ́ si iyàwó ti ọkọ rẹ̀ kú. Àṣa ṣì ṣúpó kò wọ́pọ̀ mọ laarin àwọn ti ó jade, àwọn ti ó ngbé ilú nla àti Òkè-òkun tàbi àwọn ti ó kàwé, ṣùgbọ́n ó wọ́pọ̀ laarin àwọn ti kò jade kúrò ni Abúlé àti àwọn ti kò kàwé. Idilé ti ifẹ bá wà laarin ẹbi, iyàwó pàápàá kò ni fẹ́ kúrò ni irú ẹbi bẹ́ ẹ̀ lati lọ fẹ́ ọkọ si idilé miran pàtàki nitori àwọn ọmọ tàbi ó dàgbà jù lati tun lọ fẹ ọkọ miran. Ọmọ ọkọ tàbi ẹbi ọkọ ọkùnrin lè fi àṣà yi kẹ́wọ́ lati fẹ opó ni tipátipá, omiran lè pa ọkọ lati lè jogún iyàwó. Bi iyàwó bá kú, wọn kò jẹ́ fi ọkọ rẹ jogún fún ẹbi iyàwó. Àsikò tó lati dáwọ́ àṣà ṣì ṣúpó dúró nitori obinrin ki ṣe ẹrú tàbi ẹrù ti wọn njẹ mọ́ ogún. Ìtàn Yorùbá bi Àdán ti di “Ko ṣeku, kò ṣẹyẹ” Ìtàn sọ wí pé eku ni àdán tẹ́lẹ̀ ki ìjà nla tó bẹ́ sílẹ̀ laarin eku àti ẹyẹ. Àdán rò wípé àwọn ẹyẹ fẹ́ bori, nitorina o fo lati lọ darapọ̀ mọ́ ẹyẹ lati dojú ìjà kọ àwọn ẹbi rẹ eku. Eku àti ẹyẹ bínú si àdàn nitori ìwà àgàbàgebè ti ó hu yi, wọ́n pinu lati parapọ̀ lati dojú ìjà kọ àdán. Nitori ìdí èyí ni àdán ṣe bẹ̀rẹ̀ si sá pamọ́ lati fi òkùnkùn bora ni ọ̀sán fún eku àti ẹyẹ títí di òní. A lè fi ìtàn yi wé àwọn Òṣèlú tó nsa lati ẹgbẹ́ kan si ekeji nitori ipò̀ ati agbára lati kó owó ìlú jẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, wọ́n ma “lé eku meji pa òfo” ni. Ọkùnrin ti o ni ìyàwó kan, ni àlè sita ma fara pamọ́ lati lọ sí ọ̀dọ̀ obìnrin keji ti wọ́n rò wípé́ á fún wọn ní ìgbádùn. Nígbàtí ìyàwó ilé bá gbọ́, wọn a pa òfo lọdọ ìyàwó ilé, wọn a tún tẹ́ lọ́dọ̀ àlè. Ẹ̀kọ́ ìtàn yí ni wípé iyè meji kò dara, ọ̀dalẹ̀ ma mba ilẹ̀ lọ ni, nitorina, ojúkòkòrò kò lérè. Olóri Òṣèlú Nigeria Muhammadu Buhari àti Àtẹ̀lé rẹ Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Oṣinbajo pé Ọgọrun Ọj̀ọ́ lori oye “Ìṣòro ti Agbalésanwó n ri ni Ilú Nlá lati ri Ibùgbé” Ni ayé àtijọ́, kò si ohun ti ó njẹ́ Agbalésanwó nitori kò si ẹni ti kò ni ẹbi ti wọn lè bá gbé ni ọ̀fẹ́. Kò wọ́pọ̀ ki èniyàn kúrò ni ilé lati lọ gbé ilú miran. Iṣẹ́ meji ti ó wọ́pò ni ayé àtijọ́ ni iṣẹ́ àgbẹ̀ àti òwò nipa ti ta irè oko ni ọjọ́ Ọjà Oko lati Abúlé kan si ekeji. Kò si ohun irinna bi ayé òde òni, nitorina ẹsẹ̀ ni wọn fi nlọ lati ilú kan si ekeji. Yorùbá fẹ́ràn àlejò, nitori eyi, bi Oniṣòwò bá lọ si Ọjà Oko ni ilú miran, ti kò lè délé ni ọjọ́ ti ó gbéra, yio ri ilé sùn ni abúlé ti ó bá dé ti ilẹ̀ fi ṣú lai sanwó. Olóko ni o ma npèsè ibùgbé fún Alágbàṣe ti wọn bá gbà fún iṣẹ́ oko, nitori eyi, kò si pé àlejò gba ilé lati sanwó. Ni igbà ti ó yá, èrò bẹ̀rẹ̀ si kúrò lati ilú kan si ekeji, pàtàki nitori ọ̀gbẹlẹ̀, iyàn, ogun tàbi ẹni ti wọn lé kúrò ni ilú nitori iwà burúkú. Eleyi fã ki ilú kan fẹ̀ ju òmíràn lọ, pàtàki ni ilú ti ó bá sún mọ́ odò nla bi ti ilù Èkó nitori iṣẹ́ ma npọ̀. Ni ayé òde òni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ má a nkúrò ni ilé lati wá iṣẹ́ lọ si ilú miran. Ó rọrùn fún ẹni ti ó kàwé àti oníṣẹ́ ọwọ́ lati ri iṣẹ́ nitori oriṣiriṣi iṣẹ́ pọ ni ilú nlá, ju ilú kékeré lọ. Eleyi jẹ́ ki ilú nlá bẹ̀rẹ̀ si fẹ si. Gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá “Ọ̀kọ́lé kò lè mu ràjò”, bẹni kò si bi ẹni ti ó kúrò ni ilé ti lè gbé ilé dáni lọ si ilú nlá. Àlejò bẹ̀rẹ̀ si pọ̀ si ni ilú nlá ṣùgbọ́n ilé gbigbé kò kári. Àṣà ti ó wọ́pọ̀ ni ki Onilé gba owó ọdún kan tàbi meji. Elòmìràn ngba ọdún mẹta fún owó à san silẹ̀. Ilé wá di ohun à mu ṣowó. Oriṣiriṣi àwọn oniṣẹ́ “Abániwálé” wá pọ̀ si. ọ̀pọ̀ Onilé àti Abániwále bẹ̀rẹ̀ si lu jìbìtì nipa gbi gba owó lọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ Agbalésanwó lóri ilé kan ṣoṣo, òmíràn ngba owó lóri ilé ti ki ṣe ti wọn. Yorùbá ni “Alágbàtà tó nsọ ọjà di ọ̀wọn”, bi ilé bá ti wọn tó ni owó ti Abániwále má a ri gbà ti pọ̀ tó. Eyi jẹ́ ki wọn sọ ilé di ọ̀wọ́n, nitori owó ti wọn má a ri gbà lọ́wọ́ Onilé àti Agbalésanwó lai ro inira Agbalésanwó. Oriṣi mẹta ni Yorùbá ka igbà ẹ̀dá si. Gẹ́gẹ́ bi àgbà ninú Olórin ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú Olóyè Ebenezer Obey (Fabiyi) ti kọ́ pé “Igbà mẹta ni igbà ẹ̀dá láyé, igbà òwúrọ̀, igbà ọ̀sán, igbà alẹ́, ki alẹ́ san wá ju òwúrọ̀ lọ”. Igbà meji ló wà fún ojú ọjọ́ – igbà òjò àti ẹ̀rùn. Òjò ti fẹ́rẹ̀ kásẹ̀ kúrò ni ilẹ̀ ni oṣù kẹsan ọdún nitori àsikò ìkórè sún mọ́lé lẹhin òjò. Gẹgẹ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé “Igba” ó yẹ ki enia kọ lati lo àsikò dáradára, nitori igbà kò dúró de ẹni kan. Kò yẹ ki enia fi àkókò ṣòfò, nitori ẹni kò gbin nkan, kò ni ẹ̀tọ́ àti kórè ni igbà ikórè. Ọ̀rọ̀ yi ṣe rán ẹni ti ó bá nfi àárọ̀ ṣeré leti pé bi igbà bá ti lọ, kò ṣe rà padà. “Àpẹrẹ Ẹrú ati Owó Àna fún Ìtọrọ Iyàwó ni Idilé Arinmájàgbẹ̀” Gẹ́gẹ́ bi a ti kọ tẹ́lẹ̀, ẹrù àti owó àna yàtọ̀ lati idilé kan si ekeji, ṣùgbọ́n àwọn ohun àdúrà bára mu ni ilẹ̀ Yorùbá pàtàki Oyin, Obi, Ataare, Orógbó. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbi Yorùbá, ogoji ni oye àwọn ẹrù bi Obi, Orógbó, Ataare, Ẹja-gbígbẹ àti Iṣu ti idile ma ngba. Olóri ẹbi lè din oye ẹrù ku lati din ìnáwó ọkọ iyàwó kù. Lẹhin igbéyàwó ibilẹ̀, wọn yio pin ẹrù yi (yàtọ̀ si ẹrù fún Iyàwó), si ọ̀nà meji lati kó apá kan àti apá keji fún Idilé Bàbá àti Ìyá Iyàwó. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ ẹrú ati owó àna fún Idilé Arinmájàgbẹ̀ ni Ìbòròpa-Àkókó, Ipinlẹ̀ Ondó ni ojú iwé yi. Ẹja gbigbẹ Abori Àwọn Oún ji jẹ Apẹ̀rẹ̀ ti a pin àwọn èso oriṣiriṣi wọnyi si Ohun Mimu Ọti Òyinbó Ẹrù Iyàwó Àpò Owó Ọti Òyinbó Àkàrà òyinbó Ọ̀pẹ̀ òyinbó Iwájú lèrò mbá èrò Kò si ohun téni kan ṣe, téni kò ṣe ri Ọ̀rọ̀ ijinlẹ àti Òwe Yorùbá wà lati fi kọ́ ọgbọ́n àti imò bi èniyàn ti lè gbé igbésí ayé rere. Ọ̀gá àgbà ninú Olórin ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú (Olóyè, Olùdarí Ebenezer Obey) kọ ninú orin ni èdè Yorùbá pé “ki lẹni kan ṣe, tẹni kan ò ṣe ri?” Kò si owó, ọlá, ipò, agbára ti èniyàn ni, ti kò si ẹni tó ni ri tàbi ti ẹni ti ó mbọ̀ lẹhin kò lè ni. Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé “Iwájú lèrò mbá èrò” ṣe gba ẹni ti kò bá ni ìtẹ́lọ́rùn ni ìmọ̀ràn. Ọjọ́ ori nlọ sókè ṣùgbọ́n ki wá lẹ̀. Ai ni ìtẹ́lọ́rùn ló fa ki àgbàlagbà jowú ọmọdé nitori ọmọ àná ti ó rò pé kò lè da nkankan ti da nkan, tàbi ki ọ̀gá ilé-iṣẹ́ ma jowú ọmọ iṣẹ́. Bi a bá ṣe akiyesi eré ije “Fi fa Okun” a o ri pé àwọn kan wà ni iwájú, bẹni àwọn kan wà lẹhin. Èyi fihàn pé, “Ibi ti àgbà bá wà lọmọdé mba”, ṣùgbọ́n àgbà ti ṣe ọmọdé ri. Ai ni ìtẹ́lọ́rùn lè fà ikú ójiji nitori àìsàn ẹ̀jẹ̀-riru, irònú, ijiyà iṣẹ́ ibi, olè jijà, ija, gbigbé oògùn olóró, èrú ṣi ṣe, àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ. Bi èniyàn bá kọ́ ọgbọ́n ninú ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé “Iwájú lèrò mbá èro” yi, à ri pé, kò si ipò ti òhún wà ti kò si ẹni ti ó wà nibẹ̀ ṣáájú tàbi lẹhin òhun. Ìmọ̀ yi kò ni jẹ́ ki èniyàn ṣi iwà hù, tàbi binú ẹni keji. Ó ṣe pàtàki gẹ́gẹ́ bi ikan ninú orin (Olóyè Olùdari Ebenezer Obey), pe “Ipò ki pò, ti a lè wà, ká má a dúpẹ́ ló tọ́”. “Bi ojú bá mọ́, Agbe á yalé Aláró, Àlùkò á yalé Olósùn, Lékeléke á yalé Ẹlẹ́fun” Bi a bá wo òwe yi, a o ri pe Agbe pọn bi aró, Àlùkò pupa bi osùn nigbati Lékeléke funfun bi ẹfun. Nitori eyi, bi wọn kò ti ẹ̀ lọ si ilé Aláró, Olósùn àti Ẹlẹ́fun, àwọ̀ wọn á si wa bẹ̃, síbẹ-síbẹ, àwọn ẹiyẹ wọnyi gbiyànjú lati lọ si ibi ti wọn ti lè ri ohun ti yio tú ara wọn ṣe ki ó ma ba ṣa. A lè fi òwe Yoruba ti o ni “Bi ojú bá mọ́, Agbe á yalé Aláró, Àlùkò á yalé Olósùn, Lékeléke á yalé Ẹlẹ́fun” bá ilú, agbójúlógún àti ọ̀lẹ enia wi. Kò si bi owo ilú, òbi, tàbi ẹbí ti lè pọ̀ tó, bi enia kò bá ṣiṣẹ́ kun á parun. Irú ilú ti ó bá ńná iná-kuna, agbójúlógún àti ọ̀le wọnyi yio ráhùn ni ikẹhin. Ẹ gbọ́ orin ti àwọn ọmọ ilé iwé ńkọ ni àsikò eré-ìbílẹ̀ ni ojú iwé yi. Agbe ló laró, ki ráhùn aró, Àlùkò ló losùn, ki ráhùn osùn Lékeléke ló lẹfun, ki ráhùn ẹfun, Ka má rahùn owó, Ka má rahùn ọmọ Ohun táó jẹ, táó mu kò mà ni wọn wa o) (lẹmeji) Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀, Ọba Okùnadé Alade Sijúwadé, Olúbùṣe Keji Wàjà Ni ọjọ Kejidinlọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún Ẹgbãlemẹ͂dógún, iroyin jade ninú àwọn iwé-iroyin àti ori ayélujára pé Ọba Okunade Sijuwade, Olúbùṣe Keji, pa ipò da ni Ilú Ọba. Àwọn Olóyè Ilé-Ifẹ̀ sẹ́ ọ̀rọ̀ ikú Ọba yi, nitori ni ayé àtijọ́, àwọn àgbà Oyè ló ni àṣẹ lati tú ọ̀fọ̀ pé Ọba wàjà fún ará ilú, nitori gẹ́gẹ́ bi àṣà Yorùbá Ọba ki kú. Àwọn àgbà Oyè tú ọ̀fọ̀ ni iwá́jú Gómìnà Rauf Arégbẹ́ṣọlá ti ipinlẹ̀ Ọ̀ṣun, ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kejila oṣù kẹjọ ọdún Ẹgbãlemẹ͂dógún. Ni ayé òde òni kò si àṣiri mọ, àṣà yi ti yi padà nitori, ni àtijọ́, Ọba ki kú si àjò, bẹni kò si iwé-iroyin àti ẹ̀rọ ayélujára. Ilé Ifẹ̀ jẹ́ ilú pàtàki ni ilẹ̀ Yorùbá nitori itàn sọ wi pé ibẹ̀ ni orisun Yorùbá pẹ̀lú Bàbá nla Yorùbá “Oduduwa” ti ó tẹ ibẹ̀ dó. Okùnadé Alade Sijúwadé, Olúbùṣe Keji, gun ori oyè Ọọni Ifẹ̀ nigbati ó pé aadọta ọdún, ó lo ọdún mẹ͂dógóji ni ipò Ọọni Ifẹ̀. Ohun ni aadọta Ọba Ilé Ifẹ̀. Ìsìnkú Ọba Sijúwadé bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ kẹrinla, oṣù Kẹjọ, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún. Lẹhin ìsìnkú, ìséde ọlọ́jọ́ meje yio bẹ̀rẹ̀ ni Ilé-Ifẹ̀ àti agbègbè rẹ lati agogo mẹrin ìrọ̀lẹ́. Ki Èdùmàrè gba olóògbé Ọba Sijúwadé si afẹ́fẹ́ rere. Wọn mbẹ Oníṣègùn, wọn ò bẹ Aláìsàn Yorùbá ma nlo òwe yi nigbati èniyàn bá ṣẹ̀ tàbi ṣe nkan burúkú si ẹni keji, ti wọn bẹ̀rẹ̀ si bẹ ẹni ti wọn ṣẹ̀ lai mọ bóyá ẹni ti ó ṣẹ̀ ni àyipadà ọkàn kúrò ni iwà ìbàjẹ́ tàbi iṣẹ́ ibi. A tún lè ṣe àpẹrẹ pé wọn mbẹ Adájọ́ ki ó ṣe àánú fún ọ̀daràn lai jẹ ki ó ronú ohun burúkú ti ó ṣe, ki ó lé yi padà. Oníṣègùn ninú òwe yi lè jẹ́, Òbi, Ọ̀gá ilé-iṣẹ́, Adájọ́, Ọlọpa, Ọ̀rẹ́, Ẹ̀gbọ́n, Àbúrò àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ, nigbati Aláìsàn jẹ ẹni ti ó ṣẹ̀. Lai si ìbáwí tàbi ijiyà fún ẹ̀ṣẹ̀, ẹlẹ́sẹ̀ tàbi ọ̀daràn kò ni yi padà. Nitori eyi, ó yẹ ki á bẹ alaisan, ki ó lè lo oògùn ti Oníṣègùn ṣe, ki ó bà lè ri ìwòsàn, ki wọn tó bẹ Oníṣègùn. Bi Egúngún/Eégún bá ńlé ni ki a má rọ́jú, bi ó ṣe ńrẹ ará ayé, ló ńrẹ ará Ọrun Yorùbá ma ńṣe ọdún Egúngún/Eégún ni ọdọ-dún lati ṣe iranti Bàbánlá/Ìyánlá wọn ti ó ti di olóògbé nitori wọn ni iṣẹ́ lati ṣe laarin alàyè lati rán ará ilú leti pé ki wọn di àjogúnbá ẹ̀kọ́ iwà rere mú. Yorùbá má ńpe Egúngún/Eégún ni “Ará Ọ̀run”. Egúngún/Eégún ma ńgbé ọ̀pá tàbi ẹgba lati na ẹni ti ó bá hu iwà burúkú ni àwùjọ. Fún àpẹrẹ, obinrin ti kò múra dáradára tàbi ẹni ti ó bá wọ bàtà, Eégún á le lati naa. Òwe Yorùbá ti ó ni “Bi Egúngún/Eégún bá ńlé ni ki a má rọ́jú, bi ó ṣe ńrẹ ará ayé, ló ńrẹ ará Ọrun”, ṣe gba ẹni ti ó bá wà ninú ìṣòro ni ìyànjú pé, ìṣòro yi ki ṣe ohun ti kò ni tán tàbi ni òpin. Èyi tùmọ́ si pé, ìṣòro yi á ré kọjá bi enia bá lè rọ́jú. Ni Ayé òde òni, njẹ́ ó yẹ ki a pọ́n Àṣà fi fẹ́ Iyàwó púpọ̀ lé ni Igbéyàwó Ìbílẹ̀ Yorùbá Ni igbà àtijọ́, oníyàwó kan kò wọ́pọ̀ nitori iṣẹ́ Àgbẹ̀. Àṣà fi fẹ́ iyàwó púpọ̀ ṣe kókó nitori bibi ọmọ púpọ̀ pàtàki ọmọ ọkùnrin fún irànlọ́wọ́ iṣẹ́-oko. Fi fẹ̀ iyàwó púpọ̀ kò pin si ilẹ̀ Yorùbá tàbi ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú nikan, ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Aláwọ̀funfun ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin ṣùgbọ́n nitori òwò ẹrú àti ẹ̀sin igbàgbọ́ wọn bẹ̀rẹ̀ àṣà fi fẹ iyàwó kan. Lẹhin òwò ẹrú, li lo ẹ̀rọ igbàlódé fún iṣẹ́ oko jẹ ki Aláwọ̀funfun lè dúró pẹ̀lú àṣà fi fẹ́ iyàwó kan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ ayé òde òni ti kọ àṣà fi fẹ́ iyàwó púpọ̀ silẹ̀ nitori ẹ̀sìn, ìmọ̀ àti si sá fún rògbòdiyàn ti ó lọ pẹ̀lú iyàwó púpọ̀. Iṣẹ́ Alákọ̀wé kò ṣe fi jogún fún ọmọ nitori iwé-ẹ̀ri àti ipò ti èniyàn dé ni iṣẹ́ Akọ̀wé tàbi iṣẹ́ Ìjọba kò ṣe fi jogún fún ọmọ bi oko. Owó ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Oniṣẹ́-oṣ̀u ngba kò tó lati bọ́ iyàwó kan ki owó oṣù míràn tó wọlé, bẹni kò tó gba ilé nla ti ó lè gba iyàwó púpọ̀ pàtàki ni ilú nla bi Èkó. Àṣà iyàwó púpọ̀ ṣi pọ̀, ni àwọn ilú kékeré tàbi Abúlé laarin àwọn àgbẹ̀ àti àwọn ti kò kàwé. Yorùbá ni “Bàbá, bàbá gbogbo ayé”, bi iyàwó kò bá ni iṣẹ́ lati tọ́jú ọmọ wọn, ìṣẹ́ dé, nitori eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ obinrin Yorùbá ma ntẹpá mọ́ṣẹ́ lati lè tọ́jú ọmọ wọn lai dúró de ọkọ. Ìyà àti ìṣẹ́ ni fún ọmọ púpọ̀ àti àwon iyàwó ọkùnrin ti kò ni iṣẹ́ tàbi eyi ti ó ni iṣẹ́ ti kò wúlò. Ewu ti ó wà ni ilé oníyàwó púpọ̀ ju ire ibẹ̀ lọ. Yorùbá ni “Oníyàwó kan kò mọ ẹjọ́ oníyàwó púpọ̀ da a”. Lára ewu wọnyi ni, ki i si ifọ̀kànbalẹ̀ nitori ijà àti ariwo ti owú ji jẹ laarin àwọn iyàwó ma nfà pàtàki ni agbo ilé nlá tàbi ilé Ọlọ́rọ̀ àti Olóyè. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé oníyàwó púpọ̀ ma nda ahoro lẹhin ikú Olóri ilé nitori kò si ẹni ti ó ni ìfẹ́ tọ si Bàbá oníyàwó púpọ̀. “Èèmọ̀ ni ki ọkùnrin fẹ́ ọkùnrin tàbi ki obinrin fẹ́ obinrin ni Àṣà Yorùbá ” Ilé Ẹjọ́ Àgbà yi Àṣà Ìgbéyàwó Àdáyébá padà ni ilú Àmẹ́ríka. Ni ọjọ́ Ẹti, Oṣù kẹfà, ọjọ́ Kẹrindinlọ́gbọ́n, ọdún Ẹgbãlemẹdógún, Ilé Ẹjọ́ Àgbà ti ilú Àmẹ́ríkà ṣe òfin pé “Kò si Ìpínlẹ̀ Àmẹ́ríkà ti ó ni ẹ̀tọ́ lati kọ igbéyàwó laarin ọkùnrin pẹ̀lú ọkùnrin tàbi obinrin pẹ̀lú obinrin”. Ijà fún ẹ̀tọ́ lati ṣe irú igbeyawo yi ti wà lati bi ọdún mẹrindinlãdọta sẹhin, ṣùgbọ́n ni oṣù kẹfà, ọdún Ẹgbãlemẹ́tàlá, Ilé Ẹjọ́ Àgbà fi àṣẹ si pé ki Ìjọba Àpapọ̀ gba àṣà ki ọkùnrin fẹ́ ọkùnrin tàbi ki obinrin fẹ́ obinrin, lati jẹ ki àwọn ti ó bá ṣe irú igbéyàwó yi lè gba ẹ̀tọ́ ti ó tọ́ si igbéyàwó àdáyébá – ohun ti ó tọ́ si ọkùnrin ti o fẹ́ obinrin, nipa ogún pinpin, owó ori tàbi bi igbéyàwó ba túká. Ìjọba-àpapọ̀ ti ilú Àmẹ́ríkà gba òfin yi wọlé nitori “Òfin-Òṣèlú ni wọn fi ndari ilú Àmẹ́ríkà”. Lati igbà ti ìròyìn ìdájọ́ yi ti jade, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àgbáyé, pàtàki àwọn Ẹlẹ́sin Igbàgbọ́ ti nda ẹ̀bi fún Ìjọba Àmẹ́ríkà pé wọn rú òfin Ọlọrun nipa Igbéyàwó. Ni àṣà igbéyàwó Yorùbá, èèmọ̀ ni ki ọkùnrin fẹ́ ọkùnrin tàbi ki obinrin fẹ́ obinrin. Ki ẹbi ma ba parẹ́, ọmọ bibi jẹ ikan ninú ohun pàtàki ni igbéyàwó. Bi ọkùnrin bá fẹ́ ọkùnrin, wọn ò lè bi ọmọ lai si pé wọn gba ọmọ tọ́ tàbi ki wọn wa obinrin ti yio bá wọn bi ọmọ tàbi bi ó bá jẹ laarin obinrin meji ti ó fẹ́ ara, ikan ninú obinrin yi ti lè bimọ tẹ́lẹ̀ tàbi ki ó wá ọkùnrin ti yio fún ohun lóyún ki wọn lè ni ọmọ ni irú igbéyàwó yi. Yorùbá ni “Bi a ti nṣe ni ilé wa, èèwọ̀ ibòmíràn” òfin Àmẹ́ríkà yi jẹ́ èèmọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá nitori a kò gbọ tàbi ka a ninú itàn àṣà Yoruba . Ki ṣe gbogbo èèmọ̀ ni ó dára, fún àpẹrẹ, ni igbà kan ri èèmọ̀ ni ki èniyàn bi àfin, tàbi bi ibeji nitori eyi, wọn ma npa ikan ninú àwọn meji yi ni tàbi ki wọn jù wọn si igbó lati kú, ṣùgbọ́n láyé òde òni àṣà ji ju ibeji tàbi ibẹta si igbó ti dúró. Kò yẹ ki ẹnikẹni pa ẹnikeji nitori àwọ̀ ara tàbi nitori ẹni ti èniyàn bá ni ìfẹ́ si. Ni ilú Àmẹ́ríkà ni àwọn ti ó fi ẹsin Ìgbàgbọ́ bojú ti kó si abẹ́ àwọn Aṣòfin ilú Àmẹ́ríkà ni ayé àtijọ́ pé Aláwọ̀dúdú ki ṣe èniyàn, nitori eyi, ó lòdi si òfin ki Aláwọ̀dúdú fẹ́ Aláwọ̀funfun, bi wọn bá fẹ́ra, wọn kò kà wọn kún tàbi ka irú ọmọ bẹ ẹ si èniyàn gidi. Bẹni wọn lo òfin burúkú yi naa lati pa Aláwọ̀dúdú lẹhin isin ni aarin igboro lai ya Aláwọ̀dúdú ti wọn kó lẹ́rú lati ilẹ Yorùbá sọtọ. Ogun abẹ́lé àti ṣi ṣe Òfin Àpapọ̀ tuntun lẹhin ogun, ni wọn fi gba àwọn Aláwọ̀dúdú silẹ̀ ni ilú Àmẹ́ríkà. Ki Àgbàdo tó di Ẹ̀kọ, a lọ̀ ọ́ pa pọ̀: Ògì Ṣí ṣe Àgbàdo ni wọn fi nṣe Ògì. Ògì ni wọn fi nṣe Ẹ̀kọ́. Ògì ṣí ṣe fẹ ìmọ́ tótó, nitori eyi, lai si omi, Ògì kò lè ṣe é ṣe. Ọkà oriṣiriṣi ló wà ṣùgbọ́n, Ọkà Àgbàdo àti Bàbà ni wọn mọ̀ jù lati fi ṣe Ògì funfun tàbi pupa. A lè lọ àgbàdo funfun àti pupa pọ̀, ẹlòmiràn lè lọ ẹ̀wà Sóyà pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bi àpẹrẹ àwòrán ojú iwé yi Ṣí ṣe Ògì Ra Àgbàdo lọ́jà Rẹ Àgbàdo nikan Yọ ẹ̀gbin bi ò̀kúta kúrò Si sẹ́ Àgbàdo lẹhin li lọ Ra Àgbàdo lọ́jà Da Àgbàdo rẹ fún ọjọ́ mẹta ninú omi tútù tàbi omi gbi gbóná Ṣọn Àgbàdo kúrò ninú omi lati yọ ẹ̀gbin bi ò̀kúta kúrò Gbe lọ si Ẹ̀rọ fún li lọ̀ tàbi gun pẹ̀lú odó lati lọ ọ. Sẹ́ Ògì pẹ̀lú asẹ́ aláṣọ tàbi asẹ́ igbàlódé Bẹ̀rẹ̀ si yọ omi ori Ògì si sẹ bi ó bá ti tòrò Pààrọ̀ omi ori rẹ fún ìtọ́jú rẹ fún ji jẹ tàbi Da Ògì sinú àpò ki ó lè gbẹ fún ìtọ́jú Ọba Aládélúsi Ògúnladé-Aládétóyìnbó gun Ori Oyè ilu Àkúrẹ́ Déjì Àkúrẹ́ Ọba Aládélúsi Ògúnladé-Aládétóyìnbó pari gbogbo ètùtù ibilẹ ti Ọba Àkúrẹ́ ma nṣe lati gori oyè ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹjọ, oṣù keje, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún, lati di Ọba Kejidinlãdọta ilú Àkúrẹ́ ni ipinlẹ̀ Ondó ti ila-oorun orilẹ̀ èdè Nigeria. Kábiyèsi, Ọba Aláyélúà, wo kú ori ire o Ẹbọ á fín o Àbá Adé á pẹ́ lóri, bàtà á pẹ́ lọ́sẹ̀ o Ùgbà rẹ á tu ùlú Àkúrẹ́ lára (Àṣẹ) Wi wé Gèlè Aṣọ Òfì/Òkè Aṣọ-Òfì tàbi Aṣọ-Òkè jẹ́ aṣọ ilẹ̀ Yorùbá. Aṣọ òde ni, nitori kò ṣe gbé wọ lójojúmọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Aṣọ-Òfì/Òkè wúwo, ṣùgbọ́n ti ìgbàlódé ti bẹ̀rẹ̀ si fúyẹ́ nitori òwú igbalode. Yorùbá ma nlo Aso-Oke fún Igbéyàwó, Ìkómọ, Òkú ṣi ṣe, Oyè ji jẹ, àti ayẹyẹ ìbílẹ̀ yoku. Ó dùn lati wé, ó si yẹ ni. Ẹ ṣe àyẹ̀wò wi wé gèlè Aṣọ-Òkè ninú àwòrán àti àpèjúwe ojú iwé yi: Wi wé Gèlè Ìgbàlódé Oriṣiriṣi Gèlè Aṣọ Yorùbá kò pé, lai si Gèlè. Bi Yorùbá bá wọ aṣọ ìbílẹ̀ fún òde ojoojúmọ́ tàbi fún ayẹyẹ, wọn ni lati wé gèlè ki imúra lè pé. Fún ji jade ojoojúmọ́, a lè lo ipèlé aṣọ àdirẹ àti àwọn aṣọ igbàlódé lati fi wé gèlè, ṣùgbọ́n fún òde gidi, gèlè igbàlódé tàbi Aṣọ Òfì ti wọn npe ni Aṣọ Òkè ni Yorùbá ma nwe. Eleyi jẹ ki imúra Yorùbá gbayì ni gbogbo àgbáyé. Ẹ ṣe àyẹ̀wò wi wé gèlè ni ojú iwé yi. “Gèlè ò dùn bi ká mọ̀ ọ́ wé, ká mọ̀ ọ́ wé, kò tó kó yẹni”: Aṣọ Yorùbá, ìró àti bùbá kò pé lai si gèlè. Gèlè oriṣiriṣi ló wà̀, a lè lo gèlè aṣọ ìbílẹ̀ bi: aṣọ òfi/òkè, àdìrẹ, tàbi ki á yọ gèlè lára aṣọ. Ọpọlọpọ gèle ìgbàlódé wá lati òkè òkun. Gèlè aṣọ òfì òkè ti ìgbàlódé̀ Gèlè aṣọ ànkàrá Ìmúra obinrin Yorùbá kò pé lai wé gèlè, ṣùgbọ́n òwe Yorùbá ti ó ni “Gele ko dun bi ka mo we, ka mo we, ko to ko yeni”, fihan pe ki ṣe owó ti enia ná lati ra gèlè ni ó ni kó yẹni. A lè fi ò́we yi bá awọn obinrin ti o nṣe àṣejù tabi àṣehàn, nipa ki kó owó nlá lóri àti ra gèlè lati òkè òkun. Ọ̀pọ̀ gèlè lati òkè òkun ṣòro lati wé nitorina bi enia ò bá we dáadáa, kò ni yẹni. A le fi òwe yi tún gb́ àwọn obinrin ti ó kó gèlè aṣọ-ẹbí jọ ni ìyànjú pé ki ṣe bi gèlè ṣe pọ̀ tó ló mú kó yẹni. Ẹ jẹ́ ki á ṣe ohun gbogbo ni ìwọ̀ntún-ìwọ̀nsì. “Bi a bà jẹ̀kọ à dári ji Ewé”: À-lò-tún-lò Ki ariwo à-lò-tún-lò tó gbòde ni aiyé òde òni nipa àti dáàbò bo àyíká ni Yorùbá ti ńlo à-lò-tún-lò pàtàki li lo ewé lati pọ́n oúnjẹ. Oriṣiriṣi ewé ló wà ni ilẹ̀ Yorùbá ti wọn fi má ńpọ́n oúnjẹ bi: ẹ̀kọ, ọ̀ọ̀lẹ̀/mọ́in-mọ́in, irẹsi sisè (ọ̀fadà), obì àti bẹ̃bẹ lọ. Ewé iran/ẹ̀kọ ló wọ́pọ lati fi pọ́n ẹ̀kọ, ọ̀ọ̀lẹ̀/mọ́in-mọ́in, iyán, àmàlà, irẹsi sisè àti bẹ̃bẹ lọ. Ewé obì, ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀, ewé kókò, àti àwọn ewé yókù ni iwúlò wọn ni ilé tàbi lóko. Gbogbo ewé wọnyi wúlò fún àyiká ju ọ̀rá ti wọn ńlò lati pọ́n oúnjẹ láyé òde òni. Ewé li lo fún pi pọ́n àwọn oúnjẹ kò léwu rárá bi ọ̀rá igbàlódé. Yorùbá ni “Bi a bà jẹ̀kọ à dári ji Ewé”. Òwe yi túmọ̀ si pé, bi a jẹ oúnjẹ inú ewé tán, à ju ewé nù. Ewé ti a kó sọnù wúlò fún àyiká ju ọ̀rá igbàlódé lọ. Bi wọn da ewé si ilẹ́, yio da ilẹ́ padà, bi wọn da sinú omi/odò, kò léwu fún ẹja àti ohun ẹlẹmi inú omi/odò, bi ọ̀rá àti ike igbàlódé ti ó ḿba àyiká jẹ́. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán lilo ewé lójú iwé yi. Obì ninú ewé Obì Oúnjẹ pipọ́n Ọ̀ọ̀lẹ̀ Mọ́ínmọ́ín eléwé ÌKÉDE KÁRÍAYÉ FÚN È̩TÓ̩ O̩MO̩NÌYÀN Ò̩RÒ̩ ÀKÓ̩SO̩ Bí ó ti jé̩ pé s̩ís̩e àkíyèsí iyì tó jé̩ àbímó̩ fún è̩dá àti ìdó̩gba è̩tó̩ t̩í kò s̩eé mú kúrò tí è̩dá kò̩ò̩kan ní, ni òkúta ìpìlè̩ fún òmìnira, ìdájó̩ òdodo àti àlàáfíà lágbàáyé, Bí ó ti jé̩ pé àìka àwo̩n è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn sí àti ìké̩gàn àwo̩n è̩tó̩ wò̩nyí ti s̩e okùnfà fún àwo̩n ìwà búburú kan, tó mú è̩rí‐o̩kàn è̩dá gbo̩gbé̩, tó sì jé̩ pé ìbè̩rè̩ ìgbé ayé titun, nínú èyí tí àwo̩n ènìyàn yóò ti ní òmìnira òrò̩ síso̩ àti òmìnira láti gba ohun tó bá wù wó̩n gbó̩, òmìnira ló̩wó̩ è̩rù àti òmìnira ló̩wó̩ àìní, ni a ti kà sí àníyàn tó ga jù lo̩ ló̩kàn àwo̩n o̩mo̩‐èniyàn, Bí ó ti jé̩ pé ó s̩e pàtàkì kí a dáàbò bo àwo̩n è̩tó o̩mo̩nìyàn lábé̩ òfin, bí a kò bá fé̩ ti àwo̩n ènìyàn láti ko̩jú ìjà sí ìjo̩ba ipá àti ti amúnisìn, nígbà tí kò bá sí ò̩nà àbáyo̩ mìíràn fún wo̩n láti bèèrè è̩tó̩ wo̩n, Bí ó ti jé̩ pé ó s̩e pàtàkì kí ìdàgbàsókè ìbás̩epò̩ ti ò̩ré̩‐sí‐ò̩ré̩ wà láàrin àwo̩n orílè̩‐èdè, Bí ó ti jé̩ pé gbogbo o̩mo̩ Àjo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé tún ti te̩nu mó̩ ìpinnu tí wó̩n ti s̩e té̩lè̩ nínú ìwé àdéhùn wo̩n, pé àwo̩n ní ìgbàgbó̩ nínú è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn tó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí, ìgbàgbó̩ nínú iyì àti è̩ye̩ è̩dá ènìyàn, àti ìgbàgbó̩ nínú ìdó̩gba è̩tó̩ láàrin o̩kùnrin àti obìnrin, tó sì jé̩ pé wó̩n tún ti pinnu láti s̩e ìgbéláruge̩ ìtè̩síwájú àwùjo̩ nínú èyí tí òmìnira ètò ìgbé‐ayé rere è̩dá ti lè gbòòrò sí i, Bí ó ti jé̩ pé àwo̩n o̩mo̩ e̩gbé̩ Àjo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé ti jé̩jè̩é̩ láti fo̩wó̩s̩owó̩ pò̩ pè̩lú Àjo̩ náà, kí won lè jo̩ s̩e às̩eyege nípa àmús̩e̩ àwo̩n è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn àti òmìnira è̩dá tó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí àti láti rí i pé à ń bò̩wò̩ fún àwo̩n è̩tó̩ náà káríayé, Bí ó ti jé̩ pé àfi tí àwo̩n è̩tó̩ àti òmìnira wò̩nyí bá yé ènìyàn nìkan ni a fi lè ní àmús̩e̩ è̩jé̩ yìí ní kíkún, Ní báyìí, Àpapò̩ ìgbìmò̩ Àjo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé s̩e ìkéde káríayé ti è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn, gé̩gé̩ bí ohun àfojúsùn tí gbogbo è̩dá àti orílè̩‐èdè jo̩ ń lépa ló̩nà tó jé̩ pé e̩nì kò̩ò̩kan àti è̩ka kò̩ò̩kan láwùjo̩ yóò fi ìkéde yìí só̩kàn, tí wo̩n yóò sì rí i pé àwo̩n lo ètò‐ìkó̩ni àti ètò‐è̩kó̩ láti s̩e ìgbéláruge̩ ìbò̩wò̩ fún è̩tó̩ àti òmìnira wò̩nyí. Bákan náà, a gbo̩dò̩ rí àwo̩n ìgbésè̩ tí ó lè mú ìlo̩síwájú bá orílè̩‐èdè kan s̩os̩o tàbí àwo̩n orílè̩‐èdè sí ara wo̩n, kí a sì rí i pé a fi ò̩wò̩ tó jo̩jú wo̩ àwo̩n òfin wò̩nyí, kí àmúlò wo̩n sì jé̩ káríayé láàrin àwo̩n ènìyàn orílè̩‐èdè tó jé̩ o̩mo̩ Àjo̩‐ìsò̩kan àgbáyé fúnra wo̩n àti láàrin àwo̩n ènìyàn orílè̩‐èdè mìíràn tó wà lábé̩ às̩e̩ wo̩n. Abala kìíní. Gbogbo ènìyàn ni a bí ní òmìnira; iyì àti è̩tó̩ kò̩ò̩kan sì dó̩gba. Wó̩n ní è̩bùn ti làákàyè àti ti è̩rí‐o̩kàn, ó sì ye̩ kí wo̩n ó máa hùwà sí ara wo̩n gé̩gé̩ bí o̩mo̩ ìyá. Abala kejì. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní ànfàní sí gbogbo è̩tó̩ àti òmìnira tí a ti gbé kalè̩ nínú ìkéde yìí láìfi ti ò̩rò̩ ìyàtò̩ è̩yà kankan s̩e; ìyàtò̩ bí i ti è̩yà ènìyàn, àwò̩, ako̩‐n̄‐bábo, èdè, è̩sìn, ètò ìs̩èlú tàbí ìyàtò̩ nípa èrò e̩ni, orílè̩‐èdè e̩ni, orírun e̩ni, ohun ìní e̩ni, ìbí e̩ni tàbí ìyàtò̩ mìíràn yòówù kó jé̩. Síwájú sí i, a kò gbo̩dò̩ ya e̩nìké̩ni só̩tò̩ nítorí irú ìjo̩ba orílè̩‐èdè rè̩ ní àwùjo̩ àwo̩n orílè̩‐èdè tàbí nítorí ètò‐ìs̩èlú tàbí ètò‐ìdájó̩ orílè̩‐èdè rè̩; orílè̩‐èdè náà ìbáà wà ní òmìnira tàbí kí ó wà lábé̩ ìs̩àkóso ilè̩ mìíràn, wo̩n ìbáà má dàá ìjo̩ba ara wo̩n s̩e tàbí kí wó̩n wà lábé̩ ìkáni‐lápá‐kò yòówù tí ìbáà fé̩ dí òmìnira wo̩n ló̩wó̩ gé̩gé̩ bí orílè̩‐èdè. Abala ke̩ta. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti wà láàyè, è̩tó̩ sí òmìnira àti è̩tó̩ sí ààbò ara rè̩. Abala ke̩rin. A kò gbo̩dò̩ mú e̩niké̩ni ní e̩rú tàbí kí a mú un sìn; e̩rú níní àti ò wò e̩rú ni a gbo̩dò̩ fi òfin dè ní gbogbo ò̩nà. Abala karùn‐ún. A kò gbo̩dò̩ dá e̩nì ké̩ni lóró tàbí kí a lò ó ní ìlò ìkà tí kò ye̩ o̩mo̩ ènìyàn tàbí ìlò tó lè tàbùkù è̩dá ènìyàn. Abala ke̩fà. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ pé kí a kà á sí gé̩gé̩ bí ènìyàn lábé̩ òfin ní ibi gbogbo. Abala keje. Gbogbo ènìyàn ló dó̩gba lábé̩ òfin. Wó̩n sì ní è̩tó̩ sí àà bò lábé̩ òfin láìsí ìyàsó̩tò̩ kankan. Gbogbo ènìyàn ló ní è̩tó̩ sí ààbò tó dó̩gba kúrò ló̩wó̩ ìyàsó̩tò̩ yòówù tí ìbáà lòdì sí ìkéde yìí àti è̩tó̩ kúrò ló̩wó̩ gbogbo ohun tó bá lè ti ènìyàn láti s̩e irú ìyàsó̩tò̩ bé̩è̩. Abala ke̩jo̩. E̩nì kò̩ò̩kan lórílè̩‐èdè, ló ní è̩tó̩ sí àtúns̩e tó jo̩jú ní ilé‐e̩jó̩ fún ìwà tó lòdì sí è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn, tó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí gé̩gé̩ bó s̩e wà lábé̩ òfin àti bí òfin‐ìpìlè̩ s̩e là á sílè̩. Abala ke̩sàn‐án. A kò gbo̩dò̩ s̩àdédé fi òfin mú ènìyàn tàbí kí a kàn gbé ènìyàn tì mó̩lé, tàbí kí a lé ènìyàn jáde ní ìlú láìnídìí. Abala ke̩wàá. E̩nì kò̩ò̩kan tí a bá fi è̩sùn kàn ló ní è̩tó̩ tó dó̩gba, tó sì kún, láti s̩àlàyé ara rè̩ ní gban̄gba, níwájú ilé‐e̩jó̩ tí kò s̩ègbè, kí wo̩n lè s̩e ìpinnu lórí è̩tó̩ àti ojús̩e rè̩ nípa irú è̩sùn ò̩ràn dídá tí a fi kàn án. Abala ko̩kànlá. E̩nìké̩ni tí a fi è̩sùn kàn ni a gbo̩dò̩ gbà wí pé ó jàrè títí è̩bi rè̩ yóò fi hàn lábé̩ òfin nípasè̩ ìdájó̩ tí a s̩e ní gban̄gba nínú èyí tí e̩ni tí a fi è̩sùn kàn yóò ti ní gbogbo ohun tí ó nílò láti fi s̩e àwíjàre ara rè̩. A kò gbo̩dò̩ dá è̩bi è̩s̩è̩ fún e̩nìké̩ni fún pé ó hu ìwà kan tàbí pé ó s̩e àwo̩n àfojúfò kàn nígbà tó jé̩ pé lásìkò tí èyí s̩e̩lè̩, irú ìwà bé̩è̩ tàbí irú àfojúfò bé̩è̩ kò lòdì sí òfin orílè̩‐èdè e̩ni náà tàbí òfin àwo̩n orílè̩‐èdè àgbáyé mìíràn. Bákan náà, ìje̩níyà tí a lè fún e̩ni tó dé̩s̩è̩ kò gbo̩dò̩ ju èyí tó wà ní ìmúlò ní àsìkò tí e̩ni náà dá è̩s̩è̩ rè̩. Abala kejìlá. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ pé kí a má s̩àdédé s̩e àyo̩júràn sí ò̩rò̩ ìgbésí ayé rè̩, tàbí sí ò̩rò̩e̩bí rè̩ tàbí sí ò̩rò̩ ìdílé rè̩ tàbí ìwé tí a ko̩ sí i; a kò sì gbo̩dò̩ ba iyì àti orúko̩ rè̩ jé̩. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ sí ààbò lábé̩ òfin kúrò ló̩wó̩ irú àyo̩júràn tàbí ìbanijé̩ bé̩è̩. Abala ke̩tàlá. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti rìn káàkiri ní òmìnira kí ó sì fi ibi tó bá wù ú s̩e ìbùgbé láàrin orílè̩‐èdè rè̩. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti kúrò lórílè̩‐èdè yòówù kó jé̩, tó fi mó̩ orílè̩‐èdè tirè̩, kí ó sì tún padà sí orílè̩‐èdè tirè̩ nígbà tó bá wù ú. Abala ke̩rìnlá. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti wá ààbò àti láti je̩ àn fàní ààbò yìí ní orílè̩‐èdè mìíràn nígbà tí a bá ń s̩e inúnibíni sí i. A kò lè lo è̩tó̩ yìí fún e̩ni tí a bá pè lé̩jó̩ tó dájú nítorí e̩ s̩è̩ tí kò je̩ mó̩ ò̩rò̩ ìs̩èlú tàbí ohun mìíràn tí ó s̩e tí kò bá ète àti ìgbékalè̩ Ajo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé mu. Abala ke̩è̩é̩dógún. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti jé̩ o̩mo̩ orílè̩‐èdè kan. A kò lè s̩àdédé gba è̩tó̩ jíjé̩ o̩mo̩ orílè̩‐èdè e̩ni ló̩wó̩ e̩nìké̩ni láìnídìí tàbí kí a kò̩ fún e̩nìké̩ni láti yàn láti jé̩ o̩mo̩ orílè̩‐èdè mìíràn. Abala ke̩rìndínlógún. To̩kùnrin tobìnrin tó bá ti bàlágà ló ní è̩tó̩ láti fé̩ ara wo̩n, kí wó̩n sì dá e̩bí ti wo̩n sílè̩ láìsí ìkanilápá‐kò kankan nípa è̩yà wo̩n, tàbí orílè̩‐èdè wo̩n tàbí è̩sìn wo̩n. E̩tó̩ wo̩n dó̩gba nínú ìgbeyàwó ìbáà jé̩ nígbà tí wo̩n wà papò̩ tàbí lé̩yìn tí wó̩n bá ko̩ ara wo̩n. A kò gbo̩dò̩ s̩e ìgbeyàwó kan láìjé̩ pé àwo̩n tí ó fé̩ fé̩ ara wo̩n ní òmìnira àto̩kànwá tó péye láti yàn fúnra wo̩n. E̩bí jé̩ ìpìlè̩ pàtàkì àdánidá ní àwùjo̩, ó sì ní è̩tó̩ pé kí àwùjo̩ àti orílè̩‐èdè ó dáàbò bò ó. Abala ke̩tàdínlógún. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti dá ohun ìní ara rè̩ ní tàbí láti ní in papò̩ pè̩lú àwo̩n mìíràn. A kò lè s̩àdédé gba ohun ìní e̩nì kan ló̩wó̩ rè̩ láìnídìí. Abala kejìdínlógún. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ sí òmìnira èrò, òmìnira è̩rí‐o̩kàn àti òmìnira e̩ sìn. E̩tó̩ yìí sì gbani láàyè láti pààrò̩ e̩ sìn tàbí ìgbàgbó̩ e̩ni. Ó sì fún e̩yo̩ e̩nì kan tàbí àkójo̩pò̩ ènìyàn láàyè láti s̩e è̩sìn wo̩n àti ìgbàgbó̩ wo̩n bó s̩e je̩ mó̩ ti ìkó̩ni, ìs̩esí, ìjó̩sìn àti ìmús̩e ohun tí wó̩n gbàgbó̩ yálà ní ìkò̩kò̩ tàbí ní gban̄gba. Abala ko̩kàndínlógún. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ sí òmì nira láti ní ìmò̩ràn tí ó wù ú, kí ó sì so̩ irú ìmò̩ràn bé̩è̩ jáde; è̩tó̩yìí gbani láàyè láti ní ìmò̩ràn yòówù láìsí àtakò láti ò̩dò̩ e̩nìké̩ni láti wádìí ò̩rò̩, láti gba ìmò̩ràn ló̩dò̩ e̩lòmíràn tàbí láti gbani níyànjú ló̩nàkó̩nà láìka ààlà orílè̩‐èdè kankan kún. Abala ogún. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ sí òmìnira láti pé jo̩ pò̩ àti láti dara pò̩ mó̩ àwo̩n mìíràn ní àlàáfíà. A kò lè fi ipá mú e̩nìké̩ni dara pò̩ mó̩ e̩gbé̩ kankan. Abala ko̩kànlélógún. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti kópa nínú ìs̩àkóso orílè̩‐èdè rè̩, yálà fúnra rè̩ tàbí nípasè̩ àwo̩n as̩ojú tí a kò fi ipá yàn. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ tó dó̩gba láti s̩e is̩é̩ ìjo̩ba ní orílè̩‐èdè rè̩. I fé̩ àwo̩n ènìyàn ìlú ni yóò jé̩ òkúta ìpìlè̩ fún à s̩e̩ ìjo̩ba; a ó máa fi ìfé̩ yìí hàn nípasè̩ ìbò tòótó̩ tí a ó máa dì láti ìgbà dé ìgbà, nínú èyí tí e̩nì kò̩ò̩kan yóò ní è̩tó̩ sí ìbò kan s̩os̩o tí a dì ní ìkò̩kò̩ tàbí nípasè̩ irú o̩ nà ìdìbò mìíràn tí ó bá irú ìdìbò bé̩è̩ mu. Abala kejìlélógún. E̩nì kò̩ò̩kan gé̩gé̩ bí è̩yà nínú àwùjo̩ ló ní è̩tó̩ sí ìdáàbò bò láti o̩wó̩ ìjo̩ba àti láti jé̩ àn fà ní àwo̩n è̩tó̩ tí ó bá o̩rò̩‐ajé, ìwà láwùjo̩ àti às̩à àbínibí mu; àwo̩n è̩tó̩ tí ó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí fún iyì àti ìdàgbàsókè è̩dá ènìyàn, nípa akitiyan nínú orílè̩‐èdè àti ìfo̩wó̩s̩owó̩ pò̩ láàrin àwo̩n orílè̩‐èdè ní ìbámu pè̩lú ètò àti ohun àlùmó̩nì orílè̩‐èdè kò̩ò̩kan. Abala ke̩tàlélógún. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti s̩is̩é̩, láti yan irú is̩é̩ tí ó wù ú, lábé̩ àdéhùn tí ó tó̩ tí ó sì tún ro̩rùn, kí ó sì ní ààbò kúrò ló̩wó̩ àìrís̩é̩ s̩e. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti gba iye owó tí ó dó̩gba fún irú is̩é̩ kan náà, láìsí ìyàsó̩tò̩ kankan. E̩nì kò̩ò̩kan tí ó bá ń s̩isé̩ ní è̩tó̩ láti gba owó os̩ù tí ó tó̩ tí yóò sì tó fún òun àti e̩bí rè̩ láti gbé ayé tí ó bu iyì kún ènìyàn; a sì lè fi kún owó yìí nípasè̩ orís̩ìí àwo̩n ètò ìrànló̩wó̩ mìíràn nígbà tí ó bá ye. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti dá e̩gbé̩ òs̩ìs̩é̩ sílè̩ àti láti dara pò̩ mó̩ irú e̩gbe̩; bé̩è̩ láti dáàbò bo àwo̩n ohun tí ó je̩ é̩ lógún. Abala ke̩rìnlélógún. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ sí ìsinmi àti fàájì pè̩lú àkókò tí kò pò̩ jù lé̩nu is̩é̩ àti àsìkò ìsinmi lé̩nu is̩é̩ láti ìgbà dé ìgbà tí a ó sanwó fún. Abala ke̩è̩é̩dó̩gbò̩n. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti gbé ìgbé ayé tó bójú mu nínú èyí tí òun àti e̩bí rè̩ yóò wà ní ìlera àti àlàáfíà, tí wo̩n yóò sì ní oúnje̩, as̩o̩, ilégbèé, àti àn fàní fún ìwòsàn àti gbogbo ohun tó lè mú è̩dá gbé ìgbé ayé rere. Bákan náà, e̩nì kò̩ò̩kan ló tún ní ààbò nígbà àìnís̩é̩ló̩wó̩, nígbà àìsà n, nígbà tó bá di aláàbò̩‐ara, ní ipò opó, nígbà ogbó rè̩ tàbí ìgbà mìíràn tí ènìyàn kò ní ò̩nà láti rí oúnje̩ òò jó̩, tí eléyìí kì í sì í s̩e è̩bi olúwa rè̩. A ní láti pèsè ìtó̩jú àti ìrànló̩wó̩ pàtàkì fún àwo̩n abiyamo̩ àti àwo̩n o̩mo̩dé. Gbogbo àwo̩n o̩mo̩dé yóò máa je̩ àwo̩n àn fàní ààbò kan náà nínú àwùjo̩ yálà àwo̩n òbí wo̩n fé̩ ara wo̩n ni tàbí wo̩n kò fé̩ ara wo̩n. Abala ke̩rìndínló̩gbò̩n. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti kó̩ è̩kó̩. Ó kéré tán, è̩kó̩ gbo̩dò̩ jé̩ ò̩fé̩ ní àwo̩n ilé‐è̩kó̩ alákò̩ó̩bè̩rè̩. E̩kó̩ ní ilé‐è̩kó̩ alákò̩ó̩bè̩rè̩ yìí sì gbo̩dò̩ jé̩ dandan. A gbo̩dò̩ pèsè è̩kó̩ is̩é̩‐o̩wó̩, àti ti ìmò̩‐è̩ro̩ fún àwo̩n ènìyàn lápapò̩. Àn fàní tó dó̩gba ní ilé‐è̩kó̩ gíga gbo̩dò̩ wà ní àró̩wó̩tó gbogbo e̩ni tó bá tó̩ sí. Ohun tí yóò jé̩ ète è̩kó̩ ni láti mú ìlo̩síwájú tó péye bá è̩dá ènìyàn, kí ó sì túbò̩ rí i pé àwo̩n ènìyàn bò̩wò̩ fún è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn àti àwo̩n òmìnira wo̩n, tó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí. E tò è̩kó̩ gbo̩dò̩ lè rí i pé è̩mí; ìgbó̩ra‐e̩ni‐yé, ìbágbépò̩ àlàáfíà, àti ìfé̩ ò̩ré̩‐sí‐ò̩ré̩ wà láàrin orílè̩‐èdè, láàrin è̩yà kan sí òmíràn àti láàrin e̩lé̩sìn kan sí òmíràn. E tò‐è̩kó̩ sì gbo̩dò̩ kún àwo̩n akitiyan Àjo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé ló̩wó̩ láti rí i pé àlàáfíà fìdí múlè̩. Àwo̩n òbí ló ní è̩tó̩ tó ga jù lo̩ láti yan è̩kó̩ tí wó̩n bá fé̩ fún àwo̩n o̩mo̩ wo̩n. Abala ke̩tàdínló̩gbò̩n. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láìjé̩ pé a fi ipá mú un láti kópa nínú àpapò̩ ìgbé ayé àwùjo̩ rè̩, kí ó je̩ ìgbádùn gbogbo ohun àmús̩e̩ wà ibè̩, kí ó sì kópa nínú ìdàgbàsókè ìmò̩ sáyé̩n sì àti àwo̩n àn fàní tó ń ti ibè̩ jáde. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ sí ààbò àn fàní ìmo̩yì àti ohun ìní tí ó je̩ yo̩ láti inú is̩é̩ yòówù tí ó bá s̩e ìbáà s̩e ìmò̩ sáyé̩n sì, ìwé kíko̩ tàbí is̩é̩ o̩nà. Abala kejìdínló̩gbò̩n. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ sí ètò nínú àwùjo̩ rè̩ àti ní gbogbo àwùjo̩ àgbáyé níbi tí àwo̩n è̩tó̩ òmìnira tí a ti gbé kalè̩ nínú ìkéde yìí yóò ti jé̩ mímús̩e̩. Abala ko̩kàndínló̩gbò̩n. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní àwo̩n ojús̩e kan sí àwùjo̩, nípasè̩ èyí tí ó fi lè s̩eé s̩e fún e̩ni náà láti ní ìdàgbàsókè kíkún gé̩gé̩ bí è̩dá ènìyàn. O fin yóò de e̩nì kò̩ò̩kan láti fi ò̩wò̩ àti ìmo̩yì tí ó tó̩ fún è̩tó̩ àti òmìnira àwo̩n e̩lòmíràn nígbà tí e̩ni náà bá ń lo àwo̩n è̩tó̩ àti òmìnira ara rè̩. E yí wà ní ìbámu pè̩lú ò̩nà tó ye̩, tó sì tó̩ láti fi báni lò nínú àwùjo̩ fún ire àti àlàáfíà àwùjo̩ náà nínú èyí tí ìjo̩ba yóò wà ló̩wó̩ gbogbo ènìyàn. A kò gbo̩dò̩ lo àwo̩n è̩tó̩ àti òmìnira wò̩nyí rárá, ní ò̩nà yòówù kó jé̩, tó bá lòdì sí àwo̩n ète àti ìgbékalè̩ Ajo̩‐àpapò̩ orílè̩‐èdè agbáyé. Abala o̩gbò̩n. A kò gbo̩dò̩ túmò̩ ohunkóhun nínú ìkéde yìí gé̩gé̩ bí ohun tí ó fún orílè̩‐èdè kan tàbí àkójo̩pò̩ àwo̩n ènìyàn kan tàbí e̩nìké̩ni ní è̩tó̩ láti s̩e ohunkóhun tí yóò mú ìparun bá èyíkéyìí nínú àwo̩n è̩tó̩ àti òmìnira tí a kéde yìí. Júpítérì ni plánẹ̀tì karùún láti ọ̀dọ̀ Òrùn àti plánẹ̀tì tótóbijùlọ nínú Sístẹ̀mù Òrùn. Ó jẹ́ òmìrán ẹ̀fúùfù tó ní ìsúpọ̀ tó fi díẹ̀ dín ju ìkan-nínú-ìdálẹ́gbẹ́rùún ìsúpọ̀ Òrùn lọ sùgbọ́n ìsúpọ̀ lọ́nà méjì àti àbọ̀ ti ìsúpò gbogbo àwọn plánẹ̀tì yìókù nínú Sítẹ̀mù Òrùn lápapọ̀. Júpítérì jẹ́ kìkósọ́tọ̀ bíi òmìrán ẹ̀fúùfù lápapọ̀ mọ́ Sátúrnù, Úránù àti Nẹ́ptúnù. Lápapọ̀, àwọn plánẹ̀tì mẹ́rẹ̀rin yìí jẹ́ pípè nígbà míràn bíi plánẹ̀tì Jofia. Àwọn atòràwọ̀ ayéijọ́un mọ Júpítérì, bẹ́ ẹ̀ sìni ó jẹ́ gbígbà nínú ẹ̀sìn àti àṣà àwọn ènìyàn ìgbà náà. Àwọn ará Rómù sọ orúkọ rẹ̀ fún òsa Rómù tó únjẹ́ Júpítérì. Láti Ayé, Júpítérì le ní ìhàn ìtóbi −2.94, èyí só di ohun tómọ́lẹ̀jùlọ kẹta ní ojúsànmọ̀ àṣálẹ lẹ́yìn Òsùpá àti Àgùàlà. Mársì áà le mọ́lẹ̀ bíi Júpítérì fún ìgbà díẹ̀ tó bá wà ní ààyè kan pàtó lórí ojúọ̀nàìyípo rẹ̀. Júpítérì jẹ́ ṣíṣàjọsínú pẹ̀lú háídrójìn tí ìkan-nínú-ìdámẹ́rin ìsúpọ̀ sì jẹ́ hélíọ̀m; bákannáà ó tún ṣe é ṣe kó ní inúàrin oníàpáta apilẹ̀sè wíwúwo. Nítorípé ó ún yírapo kíákíá, àwòrán Júpítérì jẹ́ bíi òbìrìkìtì afẹ̀lẹ́ẹ̀gbẹ́ (ó wú díẹ̀ síta ní agedeméjì rẹ̀). Afẹ́fẹ́ojúọ̀run òde rẹ̀ jẹ́ yíyàsọ́tọ̀ sí orísirísi ẹ̀gbẹ́ ní ojúibigbọọrọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tó ún fa ìjì àti ìṣe rudurudu lẹ́ẹ̀gbẹ́ àwọn bodè tó únkanra wọn. Ìjọba Tanzania fi Ajìjàgbara Ọmọ Orílẹ̀-èdèe Uganda sí àtìmọ́lé, wọ́n sì lé e kúrò nílùú Wairagala Wakabi, àgbà ọ̀jẹ̀ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹ̀rọ ayárabíàṣá tí ó wá láti Uganda, di ẹni àtìmọ́lé ní Pápákọ̀ òfuurufú Julius Nyerere International Airport ní Dar es Salaam, Tanzania lọ́jọ́ 25 oṣù Igbe. A fi ìwé pe Wakabi kí ó wá á sọ̀rọ̀ níbi ètò Àyájọ́ Àwọn Olùgbèjà Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Tanzania ọlọ́dọọdún tí Àgbáríjọ Olùgbèjà Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Tanzania (THRDC) jẹ́ olùgbàlejò. Wakabi ni Olùdarí Àgbà Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ètò-ìmúlò Ìmọ̀-ẹ̀rọ Gbogboògbò fún Ìlà-Oòrùn àti Gúúsù Ilẹ̀ Adúláwò (CIPESA), ọ̀kan gbòógì nínú ilé-iṣẹ́ tí ó ń ��e ètò tí ó dá lórí ètò-ìmúlò ẹ̀rọ ayélujára àti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní orí ayélujára ní ilẹ̀ Adúláwò. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí tí a fi ọ̀rọ̀ wá Wakabi lẹ́nu wò, tí wọn kò sì jẹ́ kí ó rí agbẹjọ́rò, a dá a padà sí Uganda. Àwọn aṣojú láti Àgbáríjọ Olùgbèjà Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn gbìyànjú láti jà fún un, àmọ́ a sọ fún wọn wípé fún “àǹfààní ìlú” ni a fi dá Wakabi padà sí ìlúu rẹ̀: Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò ju wákàtí díẹ̀ lọ, ó mú ìjáyà ńlá bá àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ní agbègbè náà, tí ọ̀ràn ìwà àìtọ́ tí orílẹ̀-èdèe Tanzania ń wù sí àwọn ajìjàgbara àti oníṣẹ́-ìròyìn ń peléke sí i. Nínú oṣù Belu ọdún tí ó ré kọjá, àwọn òṣìṣẹ́ Ìgbìmọ̀ tí ó ń Dáàbò bo Oníṣẹ́-ìròyìn, Angela Quintal àti Muthoki Mumo di ẹni àtìmọ́lé fún ọ̀pọ̀ wákàtí ní Dar es Salaam, Tanzania, tí ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnàa wọ́n di gbígbà lọ́wọ́ọ wọn. Human Rights Watch sọ wípé lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba Ààrẹ John Magufuli Tanzania ti rí “ìrésílẹ̀ ìbọ̀wọ̀ fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, ìkẹ́gbẹ́ àti àpéjọ dé ojú àmì” Ní ọdún-un 2015, Orílẹ̀èdè Olómìnira Ìṣọ̀kan Tanzania kéde Ìgbésẹ̀ Ìrúfin Orí Ẹ̀rọ Ayélujára. Ní àárín ọdún kan tí a kéde òfin yẹn, ó ti tó bí ọmọ orílẹ̀ èdèe Tanzania 14 tí òfín ti mú tí a sì ti dálẹ́jọ́ lábẹ́ òfin fún pé wọ́n sọ̀rọ̀ mọ́ṣààsí sí ààrẹ lórí ẹ̀rọ alátagbà. Pẹ́pẹ́yẹ gbé ọmọ pọ̀n nínú oṣù Ẹrẹ́nà ọdún-un 2018 nígbàtí a gba Ìlànà Ẹ̀rọ Ayárabíàṣá (Ohun orí ayélujára) àti Ìtàkùrọ̀sọ Ìfìwéránṣẹ́ wọlé tí ó mú un ní túláàsì fún àwọn akọbúlọ́ọ̀gù láti fi orúkọ sílẹ̀ tí wọ́n á sì san owó orí tí ó tó bíi US $900 lọ́dún kí wọn ó tó lè gbé àtẹ̀jáde sí orí ayélujára. Èyí mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ búlọ́ọ̀gù aládàádúró ó wọ òkùnkùn. Ìpalẹ́numọ́ iléeṣẹ́ akọ̀ròyìn aládàádúró nípasẹ̀ àwọn àdàlù ìṣíwèé fún ilé iṣẹ́ akọ̀ròyìn àti ìrókẹ́kẹ́ mọ́ oníṣẹ́-ìròyìn ti di ìdẹ́rùbà, ìkóra-ẹni-ní-ìjánu àti ìbẹ̀rù láti sọ èrò ọkàn ẹni nípa àwọn olórí orílẹ̀ èdè náà. Àtìmọ́lé àti ìdápadà Wakabi sí Uganda jẹ́ ìtẹ̀síwájú ìdojú-ìjà-kọ òmìnira ọ̀rọ̀ tòun èrò ọkàn ẹni ní Tanzania. Burundi: Kọ Ìkọkúkọ sórí àwòrán Ààrẹ kí o wẹ̀wọ̀n Akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà di ẹni àtìmọ́lé lọjọ́ Ìṣẹ́gun 12, oṣù Ẹrẹ́nà ní agbègbè Kirundo ní Àríwá Ìlà-oòrùn Burundi fún ẹ̀sùn-un kíkọ ìkọkúkọ sórí àwòrán Ààrẹ Pierre Nkurunziza nínú àwọn ìwé ìkọ́ni márùn-ún. Wọ́n fi ẹ̀sùn “títa àbùkù bá Ààrẹ orílẹ̀-èdè” kàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà. Ẹgbẹ́ Àwọn Àjọ tí ó ń ṣe Àmójútó ìwàlálàáfíà Àwọn ọmọdé ní Burundi jábọ̀ pé wọ́n ti fi akẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá sílẹ̀ lẹ́sẹkẹsẹ̀ nítorí pé ó ṣì kéré, kò sì tí ì tó ọdún mẹ́ẹ̀dógún. Wọ́n jábọ̀ pé wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta lọ́jọ́ Ẹtì, 15 oṣù Ẹrẹ́nà ṣùgbọ́n àwọn mẹ́ta yòókù ṣì wà ní àtìmọ́lé. Àwọn ọmọ náà tí wọn kò ju ọmọ ọdún 15 sí 17 yóò ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún bí wọ́n bá jẹ̀bi ẹ̀sùn ìtàbùkù bá Ààrẹ orílẹ̀-èdè. Ìwé ìròyìn iwacu jábọ̀ pé àwọn ìdílé tí ọ̀rọ̀ náà kàn wà nínú ìdààmú gidi. “Ìkọkúkọ [lórí àwòrán Ààrẹ] jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó mú ìjìyà dání lábẹ́ òfin ilẹ̀ Burundi gẹ́gẹ́ bí àbọ̀ ìwádìí Reuters kan ṣe sọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́-orí àwọn ọ̀daràn náà lè jẹ́ ìdí fún ṣíṣe àdínkù ìjìyà ẹ̀sẹ̀ nínú ìgbẹ́jọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí. Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kan tí kò dárúkọ araa rẹ̀ ṣe sọ, wọn kò yẹ àwọn ìwé ìkọ́ni wọ̀nyí wò fún àìmọye ọdún, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sì máa ń pín in lò ni, fún ìdí èyí ó nira láti mọ ẹni tí ó kọ nǹkan sí i ní pàtó. Ìṣẹ̀lẹ̀ tó fara jọ èyí ṣẹlẹ̀ ní 2016, lẹ́yìnin rògbòdìyàn sáà kẹ́ta Ààrẹ náà, nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ kọ ìkọkúkọ sórí àwòrán (Ààrẹ) Nkurunziza nínú ìwé ìkọ́ni. Àwọn aláṣẹ rí èyí gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀sí gidi tí wọ́n sì lé ọgọọgọ̀rún akẹ́kọ̀ọ́ kúrò ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ lóríṣìíríṣi káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kànlá ni wọ́n fẹ̀sùn ìtàbùkù bá adarí ìlú àti “ìhàlẹ̀ mọ́ ààbò ìlú” kàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n padà dá wọn sílẹ̀. Wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà yìí gidigidi. Zeid Ra'ad Al Hussein, tí ó jẹ́ aṣàkóso fún ẹ̀ka ìjàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn lábẹ́ United Nations gbé àkọsílẹ̀ kan jáde ní 29, oṣù Òkúdù 2016: Ẹ̀rù ń bà mí pẹ̀lú àwọn ìròyìn tí mò ń gbọ́ nípa lílé tí wọ́n ń lé àwọn ọmọ ní ilé-ẹ̀kọ́ àti bí wọ́n ṣe ń tì wọ́n mọ́lé nítorí ìkọkúkọ tí wọ́n kọ sórí àwòrán Ààrẹ nínú àwọn ìwé ìkọ́ni. Pierre Nkurunziza ti jẹ ààrẹ ilẹ̀ Burundi láti ọdún 2005. Ní ọdún 2015, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlúu rẹ̀ tún gbé e sípò fún sáà kẹ́ta lórí oyè. Ní oṣù Ẹrẹ́nà ọdún tó kọjá, Nkurunziza gba orúkọ tuntun lọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlúu rẹ̀, Àjọ Agbèjà Òmìnira Àwọn Ológun – Fún Ìgbéga Ìjọba Oníbò (CNDD-FDD). Wọ́n pè é ní “adarí ayérayé tó ga jù”. Akọ̀wé gbogboògbò fún CNDD-FDD, Evariste Ndayishimiye ṣàlàyé ìdí tí orúkọ náà ṣe di ti Nkurunziza: Olùdaríi wa ni, kò sí eni tí a lè fi wé e nínú ẹgbẹ́ẹ wa. Òun ni òbíi wa, òun ni ó ń gbà wá nímọ̀ràn. Ìdí nìyí tí mo ṣe ní kí gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ pọ́n ọn lé nítorí pé ojúkójú ni ẹnikẹ́ni lè fi wo ilé tí kò ní olórí. Ní tiwa, olórí tó dára jù ni a ní. Bí àwọn CNN-FDD ṣe gbé oyè náà ní yẹpẹrẹ tó ipò agbára Nkurunziza gẹ́gẹ́ bí adarí ayérayé tó ga jù ti jẹ́ kí ó nira fún ẹnikẹ́ni láti kọ ohunkóhun tí ó bá yàn láti ṣe, títí mọ́ ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti ṣe àyípadà òfin sáà méjì fún ipò adarí tí ó wà nínú ìwé òfin orílẹ̀-èdè náà. Èyí ń ṣe àfihàn àdálò tí ẹgbẹ́ òṣèlú tó wà lórí oyè ń dá agbára lò pẹ̀lú Nkurunziza àti àwọn alátìlẹyìn-in rẹ̀ pẹ̀lú bí ẹgbẹ́ òṣèlú náà ṣe ń darí àwọn ìdásílẹ̀ ìjọba. Àwọn oníkọkúkọ ní ìṣọ̀kan Àwọn ọmọ ìlú tí wọ́n ń ṣàmúlò ayélujára ti bẹ̀rẹ̀ ìkọkúkọ sórí àwòrán ààrẹ Nkurunziza nínú ìfẹ̀hónúhàn pẹ̀lú àmì ìdámọ̀: Nkurunziza àti Burundi: Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ní ẹ̀wọ̀n fún kíkọ ìkọkúkọ sí orí àwòrán Ààrẹ . Bí mo bá ṣe èyí ní Burundi , ó ṣe é ṣe kí a fi mí sí àtìmọ́lé Ìjọba Burundi fi akẹ́kọ̀ọ́bìnrin sí àtìmọ́lé látàrí ẹ̀sùn ìkọkúkọ sí orí àwòrán ààrẹ. A túwíìtì àwòrán ìkọkúkọ wa ní ìbánikẹ́dùn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Wọ́n ní kí a dán an wò, kí a kọ nǹkan sí orí àwòrán ààrẹ mo sì ṣe bẹ́ẹ̀. Mo ní ìgbóyà wípé ẹnikẹ́ni kò ní mú mi níbí. Ìfòfinlíle mú àtakò Ìjọba Burundi ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìkanra mú ìwà àtakò láti ọdún 2015, lẹ́yìn ìjákulẹ̀ ìṣọ̀tẹ̀ kan, ìdojúkọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ adìtẹ̀ kan, àtakò lórí ìlòkulò ẹ̀tọ́, òfin kànńpá, ìnira pẹ̀lú ètò ọrọ̀-ajé àti rògbòdìyàn àwọn asásàálà. European Union pẹ̀lú United Nations tako ìgbésẹ̀ Nkurunziza fún sáà kẹ́ta, wọ́n sì béèrè fún ìdápadà ìlọdéédé kí àsìkò ìdìbò ó tó dé. Pẹ̀lú àwọn ìdojúkọ wọ̀nyí, “ipò náà” le sí i. Àwọn aláṣẹ sì ń fi ìkanra mú gbogbo ìhàlẹ̀ tí wọ́n ń rí. Ìjábọ̀ pàtàkì ti àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn ṣe ní oṣù Èbìbí 2018 rí i pé àwọn èṣọ́ aláàbò ní Burundi, àwọn afòyeṣiṣẹ́ àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó wà nípò, àwọn ẹgbẹ́ Imbone… ń kọlu àwọn alátakò àti àwọn ẹni tí wọ́n fura sí gẹ́gẹ́ bí alátakò pẹ̀lú ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn àti akọ̀ròyìn. “Wọ́n pa èèyàn tó tó 1700, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń fi ipá lé àwọn ẹlòmíìn, wọ́n ń fi ipá bá wọn ní ìbálòpọ̀, wọ́n ń fi ìyà jẹ wọ́n, wọ́n ń tì wọ́n mọ́lé, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń dẹ́rùba àìmọye àwọn mìíràn”. Èyí ti dá wàhálà ìsásàálà sílẹ̀, a ti rí àwọn ará Burundi tí wọ́n sá lọ sí Tanzania, Rwanda, Congo àti Uganda. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ti padà sílé. Alákòóso United Nations fún ìsásàálà ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn asásàálà tí ó wá láti Burundi tí wọ́n lé ní 347,000 ní oṣù Èrèlé 2019, UNHCR fìdí ẹ̀ múlẹ̀: Làásìgbò nínú òṣèlú Burundi le sí i ní ọdún 2015 lẹ́yìn tí ààrẹ́ kéde èròńgbàa rẹ̀ láti lọ fún sáà kẹ́ta. Ìfẹ̀hónúhàn àwọn èèyàn láti tako èròńgbà fa ��kọlura, ọgọọgọ̀rún àwọn èèyàn sì sá lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè ìtòsí láti fi oríi wọn pamọ.” Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, ìjọba Burundi ti ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn lábẹ́ United Nations tí wọ́n sì sọ pé àwọn kò nílòo wọn mọ́. Ìjọba náà ń bínú sí alákòóso tẹ́lẹ̀-rí ẹ̀ka náà, Zeid Ra'ad Al Hussein tí ó ṣàpèjúwe Nkurunziza ti Burundi gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára “àwọn apanilẹ́kúnjayé ènìyàn tí ó ń gbèrú sí i láìpẹ́ yìí” ní oṣù Èrèlé 2018. Àtipa àwọn Ilé-iṣẹ́ Akọ̀ròyìn, ìyọlẹ́nu àwọn alátakò, ìfòfinlíle mú àwọn ìdásílẹ̀ tí kì í ṣe ti ìjọba (NGOs) àti ìdiwọ́ fún àwọn mìíràn láti sọ̀rọ̀ tàbí ṣe àfihàn ara wọn ní ààyè òṣèlú. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélọ́gbọ̀n fún ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn Germain Rukiki fún “ìdarapọ̀ mọ́ ìgbìyànjú ìrúlùú, “jíjin ètò ààbò ìlú lẹ́sẹ̀, àti ìṣọ̀tẹ̀” ní 2018 nítorí pé ó ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀nà tí ìjọba Nkurunziza ń gbà fìyà jẹni. Àwọn àìṣedede kan dá ìgbẹ́jọ́ Rukiki dúró, ó sì wáyé ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú àríyànjiyàn ìdìbò abófinmu náà. “Ọ̀rọ̀ ìkọkúkọ” náà ń ṣe àfihàn ìdúróṣánṣán ìjọba náà tí kò yẹ̀ àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe ẹ̀tọ́ọ wọn, títí mọ́ ṣíṣe ìgbéyàwó kànńpá fún àwọn tọkọtaya tí wọ́n ń gbépọ̀ láìṣe ìgbéyàwó ní 2017: ìfòfinlíle mú òwòo panṣágà àti agbe ṣíṣe. Àfilé iye owó fún gbígba ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà mú àwọn ọmọ Angola fi ẹ̀hónú hàn Inú ń bí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Angola látàrí iye owó ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà tuntun 30,500 kwanzas (ó tó 97 owó dollar) tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ polongo ní ọjọ́ 21 oṣù Ṣẹẹrẹ. 2500 kwanzas (owó dollar orílẹ̀-èdè US mẹ́jọ) ni ó jẹ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Ní àfikún, ìjọba ti pín iye owó irúfẹ́ ìrìnàjò tí ó wà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó tò ó ní ẹsẹẹsẹ. Lábẹ́ ìlànà tuntun yìí ni ìjọba yóò ti máa gba 45,250 kwanzas fún ìwé ìwọ̀lú ìdúró-sí-ìlú; 21,350 fún ìwé ìwọ̀lú ìrìnàjò-afẹ́; 36,500 fún ìwé ìwọ̀lú àgbàníbodè; 38,125 fún ìsúnsíwájú ìwé ìwọ̀lú iṣẹ́; 15,250 fún ìwé ìwọ̀lú ọ̀rọ̀ ìlera ara; àti 30,500 fún ìwé pélébé ìgbélùú. Agbẹnusọ fún Ẹ̀ka Ìjọba tí ó ń ṣe àbójútó ètò ìforúkọsílẹ̀, Valdemar José, sọ fún àwọn akọ̀ròyìn ìbílẹ̀ Angola pé ìdíyelé fún ìwé ìrìnnà ìwọ̀lú lásán-làsàn lọ sí òkè nítorí owó gegere ni ó ń jẹ láti ṣe ìwé náà: Ìjọba rí i wípé ó tó àsìkò láti sún owó ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà, ó sì ti yọ ọwọ́ọ Kílàńkóo rẹ̀ kúrò nínú kíkó owó lé e lórí, kí ó ba lè ṣe, fún àpẹẹrẹ, pèsè omi, ináa mànàmáná àti àwọn ohun amáyérọrùn mìíràn. Ohun èlò fún ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà máa ń gbọ́n owó mì, nítorí iṣẹ́ ìdáàbòbò oríi rẹ̀, tí àjọ ọba ń kówó lé lórí tẹ́lẹ̀ kí ó tó di ìgbà yìí. Èyí jẹ́ ìrántí ohun tí ojú àwọn ọmọ Mozambique rí ní ìparí ọdún-un 2018, nígbàtí ìjọba pinnu láti fi owó kún ìwé àṣẹ gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni ó bá ìwé àṣẹ ọkọ̀ wíwà, tí ìdíyelée rẹ̀ fi ìdá 500 gbéwó lórí. Àfilé iye owó náà ti dá awuyewuye sílẹ̀. Ìfẹ̀hónúhàn ọ̀dọ̀ tí ó tó bíi 100 wáyé ní ọjọ́ kẹ́rin oṣù Èrèlé, pẹ̀lú àtìlẹ́yìn ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ìlú kan tí ó rí ìgbésẹ̀ ìjọba gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn fún ìrìnàjò ṣíṣe. Ìfẹ̀hónúhàn náà Ní ọjọ́ kẹrin oṣù Èrèlé, Global Voices bá Fernando Gomes, ajìjàǹgbara ọmọ orílẹ̀ èdè Angola tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alátìlẹ́yìn ìfẹ̀hónúhàn náà tàkùrọ̀sọ, láti mọ ohun gbogbo tí ó rọ̀ mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó sọ fún wa: Èyí [ni ọ̀nà kan] fún ìpèsí àkíyèsí ìjọba João Lourenço, wípé àfilé ìdíyelé kò yẹ nírú àsìkò yìí, nítorí owó náà ti ṣe gegere ju fún àwọn ọmọ ìlú. (…) Àti pé “iṣẹ́ ìdàgbàsókè ọrọ̀ Ajé orílẹ̀-èdè Angola” kò lé wáyé nípasẹ̀ àfilé owó orí, nítorí wípé àwọn ọmọ ìlú ni ó ń fi orí kó o, àwọn tí ó wà ní ipò ìjọba ní àǹfààní tí ó pọ̀ ní ìkáwọ́ọ wọn, tí ó ṣe pé àpò ará ìlú tí ó ń rùnpà ni wọ́n ti ń mú owó tí wọ́n ń ná. Àwọn alátakò ti sọ pé ó ṣe pàtàkì láti rántí wípé ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà dúró fún ìdánimọ̀ ọmọ ìlú ní òkè òkun, torí ìdí èyí, kò ṣe é yẹ̀ sílẹ̀ fún wọn. A máa wà ní ojú òpópónà ní olú ìlú fún oṣù Èrèlé, ní àwọn ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí a yàn, ọjọ́ kẹrin oṣù Èrèlé ni ìwọ́de náà bẹ̀rẹ̀, àmọ́ ní ọjọ́ kéje ni a máa padà sí ojú òpópónà, tí a óò tún wà ní ọjọ́ kankànlá, tí a ó sì jábọ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá, bí ìjọba kò bá yí ohùn padà. Àwọn akọrin ewì-alohùn ráàpù, Lilo Kwanza àti Adérito Gonçalves, kọ orin kan, tí wọ́n sì ya àwòrán-an orin tí ó dá lóríi ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn yìí, “Ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà 30,000″ ni àkọlé orin náà, tí ó ń ṣe ẹ̀fẹ̀ lórí iye owó tabua tí ọmọ-ìlú yóò san fún ìwé ìrìnnà. Ó ku ọjọ́ díẹ̀ kí ìwọ́de náà ó kò, ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Angola Pedrowski Teca sọ wípé ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnná pọn dandan ju ìwé ìdánimọ̀ pélébé lọ, ó rọ àwọn ènìyàn láti kọ́wọ̀ọ́ rìn, nítorí àìkọ́wọ̀ọ́ rìn, ní í ṣe ikú pa ọmọ ejò: Àwọn àjọ àgbáyé ti dẹ̀yìn kọ Òfin Ìṣíkúrò tí ó pàṣẹ àfilé ìdíyelé tí ó gbéra nílẹ̀ fìrì tí ó sì lọ òkè lálá. Ìwé ìdánimọ̀ pélébé (B.I) wúlò gẹ́gẹ́ bí àmì ìdánimọ̀ ní àárín ìlú Angola. Ní ẹ̀yìn odi ìlú Angola, pánda tí kò wúlò ni ìwé ìdánimọ̀ pélébé, kò sí àmì ìdánimọ̀ kan tí ó wà bí kò ṣe ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà. Àwa, tí a wà nínú ìlú, ni a ó fi ààbò bò tí a ó sì ké pe àwọn aráa wa ní òkè òkun, kí àwọn náà ó ké gbàjarè, nítorí ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà ṣe kókó fún wọn. Kí ìròyìn náà ó ba hó ye létí àwọn ènìyàn, ajàfúnẹ̀tọ́ọ nì àti akẹ́kọ̀ọ́ Ifáfitì, David Mendes, kọ, ní ọjọ́ ìwọ́de náà, iṣẹ́-ìjẹ́ fún ààre orílẹ̀-èdè Angola João Lourenço: Ọmọ-ẹgbẹ́ ààrẹ João Lourenço, kì í ṣe nítorí èyí ni àwọn aráa Angola ṣe yàn ọ́ sípò, kò sí ibi tí o ti sọ nínú ìpolongo ìléríi rẹ, o kò sọ pé ìwé ẹ̀rí yóò gbówó lórí, síbẹ̀ kí ni ò ń rò? Kí ni ẹ fi ṣe ohùn àwọn mẹ̀kúnnù? A ti rí ìrora látàrí àwọn àfilé ìdíyelé, ǹjẹ́ o mọ ìṣòro tí ó ń fà fún àwọn ará ìlú? A kò tilẹ̀ mọ ẹni náà tí ó tọ́ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè Angola, báwo ni ọ̀dọ́ tí kò níṣẹ́ tí kò lábọ̀ yóò ṣe rí owó gba ìwé ẹ̀rí? Pẹ̀lú gbogbo rẹ̀, ìjọba kò ì tíì sọ tó, tàbí kí ó kéde láti sọ bóyá òun yóò mú ìdíyelé náà wálẹ̀. Àwọn ọ̀gágun ajagun fẹ̀yìntì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wọ̀yáàjà láti nípa lórí ètò ìdìbò ọdún-un 2019 Bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe ń múra fún ètò ìdìbò sí ipò Ààrẹ nínú Oṣù Èrèlé, àwọn ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì tí wọn di olóṣèlú, jẹ́ igi gbòógì fún òye ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn ọ̀gágun tí ó ti fẹ̀yìntì tàbí àwọn tí wọn ṣe àtìlẹ́yìn fún láti dé orí ipò ni ó ti ń tukọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọdún 1999 tí ìjọba tiwantiwa ti padà. Asọ̀ tí ó wáyé láìpẹ́ yìí láàárín Ààrẹ àná, Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ àti Ààrẹ tí ó wà lórí àlééfà, Ààrẹ Muhammadu Buhari – tí àwọn méjèèjì jẹ́ ajagun fẹ̀yìntì afipásèjọba ológun –ní ipa tí ó pọ̀ lórí ètò ìdìbò oṣù tí ó ń bọ̀. Nínú ìwé àpilẹ̀kọ kan tí a kò rí irúu rẹ̀ rí tí ó kọ ránṣẹ́ sí Buhari, Ọbásanjọ́ fi ẹ̀sùn kàn-án wípé ó ní ètè láti ṣe èrú ìbò. Ó kọ ọ́ sínú ìwé náà wípé: Ìtìjú ńlá gbáà ló jẹ́ fún ìjọba tiwantiwa, bí ètò ìbò tí o yẹ kí ó lọ ní ìrọwọ́-ìrọsẹ̀ láì fi ti apá kan ṣe, ṣùgbọ́n tí ìṣesíi wọn kò fi ìṣedéédé hàn, àìmúdọ́gba tí ó hàn kedere, ẹ̀tàn àti ìjòye àwòdì máà le è gbẹ́dìẹ. Ọbásanjọ́ tẹnu mọ́ ọn wípé Buhari kò leè “ṣe ètò ìbò tí ó kẹ́sẹjárí”, àti wípé ìsèjọba tiwantiwa ní abẹ́ ìṣàkóso Buhari ni a lè fi wé tí ìjọba ológun fàmílétè-kí-n-tutọ́ọ ti Abacha. Ní ọdún 1998, Sani Abacha, tí ó jẹ́ ológun apàṣẹwàá ní ìgbà náà, pè fún ìbò gbogboògbò ṣùgbọ́n tí ó hàn ketekete pé Abacha kò ṣetán láti gbé ìjọba sílẹ̀ fún alágbádá. Ní àsìkò tí à ń sọ̀rọ̀ọ rẹ̀ yìí, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó fọwọ́ síi wípé kí Abacha ó jẹ́ olùdíje fún ipò Ààr�� nínú ẹgbẹ́ òṣèlúu wọn. Ní báyìí ó ti ṣípò-padà, òkìkí Abacha tàn káàkiri ó sì di ìlú-mọ̀-ọ́-ká nípa ìtẹrí ẹ̀tọ́ ọmọ-ènìyàn mọ́lẹ̀ àti ìjẹgùdùjẹrà. Ọbásanjọ́ tẹnumọ́ọ wípé “ipasẹ̀” Abacha ní ọjọ́ kínní àná náà ni Buhari ń tọ́ báyìí “láì wo ẹ̀yìn wò.” Shehu Garba, tí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Ààrẹ Buhari lórí gbígbé ìròyìn jáde, bu ẹnu àtẹ́ lu ìwé àpilẹ̀kọ Ọbásanjọ́: Ètò ìdìbò tí yóò wáyé nínú osù tí ó ń bọ̀ yìí yóò lọ ní pẹ̀lẹ́-kùtù, gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Buhari ti ṣe ìlérí fún ọmọ orílẹ̀-èdè yìí àti àgbáyé. Ọbásanjọ́, òǹkọ̀wé àpilẹ̀kọ? Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, tí ó jẹ́ Ààrẹ ìjọba ológun àná (láti ọdún 1976 sí 1979), tí ó sì tún ṣe Ààrẹ ìjọba alágbádá tí ìbò gbé wọlé (ní ọdún 1999 sí 2007), kúndùn láti máa bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ètò ìjọba Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó jẹ tẹ̀lé e. Ní èṣí, Ọbásanjọ́ gba Buhari ni ìmọ̀ràn láti má díje fún ipò Ààrẹ fún ìgbà kejì, ṣùgbọ́n kí ó “da ìfẹ̀yìntì rò nítorí ọjọ́ oríi rẹ̀.” Àmọ̀ràn yìí dá yánpọnyánrin sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nítorí wípé Ọbásanjọ́ jẹ́ alátìlẹ́yìn àgbà fún Buhari gẹ́gẹ́ bí òǹdíje nínú ìbò ipò Ààrẹ ni sáà àkọ́kọ́ ní ọdún 2015. Ṣáájú àsìkò yìí, Ọbásanjọ́ ti bá ìjọba Goodluck Jónátánì wí nínú ìwé àpilẹ̀kọ tí ó kọ ránṣẹ́ sí i ní ọdún 2013, Ọbásanjọ́ fi ẹ̀sùn kan Jónátánì wípé ó ń darí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ sí oko ìparun pẹ̀lú bí ó ṣe fi àyè gba ẹ̀tàn, ìjẹ́gùdùjẹrà, ìbápín àìgbẹ́kẹ̀lé láti fa aṣọ iyì àti ìtẹ̀síwájú orílè-èdè náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” Ní àpárá, Ọbásanjọ́ ti Goodluck Jónátánì lẹ́yìn nínú ètò ìdìbò tí ó wáyé ní ọdún 2011. Àti wípé ni ọdún 2007, òun yìí kan náà ni ó ti Umaru Musa Yar'Adua tí ó jẹ kí Jónátánì ó tó jẹ lẹ́yìn digbídigbí. Ṣùgbọ́n tí ó pa ìdí ọ̀rẹ́ dá sí Yar'Adua lẹ́yìn ìgbátí ó bẹ̀rẹ̀ àìsàn tí kò sì gbé ètò ìṣe ìjọba fún igbákèjì rẹ̀ tii ṣe Goodluck Jónátánì. Ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì kì í sinmi ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Abẹ ìgbèkùn àwọn ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì àti àwọn asọ́mogbée wọn ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà. Bí àpẹẹrẹ, Ọbásanjọ́ jẹ́ alẹ́nulọ́rọ̀ tí ó mọ àludé tòun àpadé bí àwọn Ààrẹ ṣe ń gba ipò láti ọdún 2007 sí 2015. Bíótiwùkíórí, láì jọ ti àwọn alágbádá – Yar'Adua àti Jónátánì – tí ó gbé ní arugẹ, tí ó sì tún yẹpẹrẹ wọn, ti Buhari dá yàtọ̀ gedegbe. Bí ó ti lẹ̀ jé pé Ọbásanjọ́ ti Buhari lẹ́yìn láti leè yege ní ọdún 2015, a kò leè sọ pé àtìlẹyìn rẹ̀ nìkan ni ó gbé e dé ipò Ààrẹ. Nítorí ohun tí ó jẹ́ kí ó ṣeé ṣe ò ju bí Buhari ṣe fi ọwọ́ wẹ ọwọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú ìgbàanì Action Congress of Nigeria (ACN) ti Bọ́lá Tinubu. Ẹgbẹ́ òṣèlú Congress for Progressive Change (CPC) ti Buhari jẹ ọmọ ẹgbẹ́ ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín parapọ̀ mọ́ ACN, wọ́n sì di ọkàn nínú oṣù Kejì ọdún 2013, èyí tí ó ṣe okùnfà ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú Gbogboògbò (APC). Ní àfikún, Buhari tí ó ṣe olórí ìjọba ológun ní ọdún (1983 sí 1985) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ‘ẹgbẹ́’ ọ̀gágun tí ó ti fẹ̀yìntì tí ó ti takú ti ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Fún ìdí èyí, bí Ọbásanjọ́ ṣe tàbùkù Buhari ní gbangba tó, ó níí ṣe pẹ̀lú agbára àti ipò ẹgbẹ́ tí àwọn méjèèjì wà gẹ́gẹ́ bí ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì. Ọbásanjọ́ nìkan sì kọ́ ni ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì tí ó ń tàbùkù Buhari. Theophilus Danjuma, tí òun náà jẹ́ ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì ní oṣù kẹ́ta ọdún tí ó kọjá fi ẹ̀sùn kan “ẹgbẹ́ ológun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wípé ó ń gbárùkù ti ìpànìyàn nípakúpa tí ó ń lọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.” Danjuma, tí ó jẹ olórí àwọn ológun, tí o si tún jẹ́ mínísítà fún ètò abo ní ìgbà kan rí, bu ẹnu àtẹ́ lu ẹgbẹ́ ológun bí wọ́n ṣe ń gbé lẹ́yìn apá kan dá apá kan sí nínú aáwọ̀ tí ó wáyé láàárín àwọn darandaran àti àgbẹ̀, pàápàá jù lọ èyí tí ó wáyé ní ilée rẹ̀ tí í ṣe ìpínlẹ̀ Taraba. Ìrí-bá-kan-náà, Danjuma fi ariwo ta nípa ète bí àwọn “ọlọ́pàá àti ológun” ṣe ń gbìmọ̀pọ̀ láti ṣe ẹ̀rú nínú ìbò ọdún 2019. Bákannáà ẹ̀wẹ̀wẹ̀, nínú Oṣù Kejì ọdún tí ó kọjá, ajagun fẹ̀yìntì tí ó tún jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láyé ológun, Ibrahim Babangida gba Ààrẹ Buhari ní ìyànjú láti máà du ìje fún ipò Ààrẹ fún ìgbà kejì, nítorí wípé ọgọ́rùn-ún ọdún 21 tí Nàìjíríà wà yìí jẹ́ àsìkò àwọn ọ̀dọ́ tí ó ní ìrírí ìgbàlódé. Ó gbàgbọ́ wípé ìgbàkanìgbàkàn “ohun tí yóò jẹ́ àǹfààní gbogbo ará ìlú gbọdọ̀ bo orí àǹfààní ti ara ẹni.” Pẹ̀lú bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ, yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ pẹ́ díẹ̀ kí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ó tó le è ní Ààrẹ tí kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú, tàbí tí kò ní àtìlẹ́yìn ‘ẹgbẹ́’ àwọn ọ̀gágun ajagun fẹ̀yìntì. Mọ àwọn òǹdíje sí ipò ààrẹ Nàìjíríà ọdún 2019 Nàìjíríà, orílẹ̀-èdè tí ó ní ènìyàn tí ó pọ̀ jù ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀, yóò di ìbò ipò ààrẹ ní ọjọ́ 16, oṣù 2019. Bí-ó-ti-lẹ̀-jẹ́-wípé àwọn òǹdíje sí ipò ààrẹ t'ó 73, eré Àpáta Agbára – ibùjókòó ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà – yóò wáyé ní àárín-in ẹgbẹ́ olóṣèlú méjì tí ó ti ń figagbága ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́ àti àwọn òǹdíje tí a pè ní “agbára ìkẹta”, ìyẹn àwọn ẹgbẹ́ a ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sínú ìṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ẹgbẹ́ méjèèjì tí ó gbajúmọ̀ jù lọ, Ìpéjọ Ìlọsíwájú Gbogboògbò APC àti Ẹgbẹ́-olóṣèlú Ìjọba-àwa-arawa PDP, láì ṣe àní-àní, yóò tari òǹdíje wọn sí gbangba wálíà: Muhammadu Buhari Ààrẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ tí ó jẹ́ òǹdíje lábẹ́ àsíá APC, Buhari ló jáwé olúborí nínú ìbò ààrẹ ti ọdún 2011 tí ààrẹ ìgbà kan Goodluck Jónátánì sí pàdánù. Nítorí irú ènìyàn tí Buhari ń ṣe àti èrò wípé yóò gbógun ti ìjẹgúdújẹrá àti ìgbáwọlẹ̀ ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò Boko Haram ni àwọn ará ìlú fi gbé e sórí àlééfà. Síbẹ̀, lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀, ààbò ẹ̀mí kò sí pẹ̀lú ìkọlù láàárín darandaran àti àgbẹ̀ bí àwọn darandaran láti àríwá ṣe ń wọ gúúsù láti wá koríko fún ẹran ọ̀sìn-in wọn. Bákan náà, ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ti wó lulẹ̀ nínú ìṣàkóso ìjọba rẹ̀, pẹ̀lú àìjẹ̀yà àti ìṣowó-ìlú-mọ̀kumọ̀ku ní ibi gíga nínú ìjọba. Atiku Abubakar Abubakar ni igbá-kejì ààrẹ ìgbà kan àti òǹdíje lábẹ́ àsíá PDP. Ó ti gbìyànjú sẹ́yìn láti di ààrẹ àmọ́ orí kò ṣe ní oore. Bíótiwùkíórí, ìpolongo rẹ̀ jẹ́ ìgbàwọlé nítorí ìparí ìjà tí ó wà ní àárín òun àti ọ̀gáa rẹ̀, Ààrẹ ìgbà kan rí Olusegun Obasanjo tí ó sọ wípé ìṣàkóso ìjọba Buhari kùnà. Gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́, Abubakar ni ó ṣe bònkárí ìsọhun-ìjọba-di-àdáni àti títa ọ̀kẹ́ àìmọye ilé iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti ìjọba tí kò pa owó sí àpò ìjọba. Àwọn mìíràn tí ó ní ìrètí sí ipò ààrẹ Nàìjíríà ni: Obiageli Ezekwesili Ezekwesili, obìrin kan ṣoṣo tí ó ń du ipò nínú eré ìbò sísá ti ọdún tí a wà yìí, ti ṣe mínísítà ọrọ̀ líle inú-ilẹ̀ àti ètò ẹ̀kọ́ ní àsìkò ìjọba Olusegun Obasanjo ní àárín ọdún 1999 sí 2007. Ó sì ti ṣe amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ààrẹ Ilé ìfowópamọ́ Àgbáyé ẹ̀ka ti Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ìgbà kan láti oṣù Igbe ọdún 2007 sí oṣù Igbe ọdún 2012. Ezekwesili ti ṣe bẹbẹ nínú akitiyan ìdásílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́-bìnrin 200 tí ọmọ ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfo Ẹlẹ́sìn ìmale jí gbé ní ọdún 2014. Ó jẹ́ ọ̀kan lára olùdásílẹ̀ Ìpolongo BringBackOurGirls . Bákan náà ni ó jẹ́ òǹdíje sí ipò ààrẹ ní abẹ́ ẹgbẹ́ olóṣèlú Allied Congress Party ti Nàìjíríà. Kingsley Moghalu Moghalu jẹ́ onímọ̀ nínú ìdókòwò àgbáyé àti òfin gbogbo ènìyàn ní ilé ìwé Òfin àti Ọgbọ́n Fletcher ní Ifásitì Tufts ní Massachusetts, USA. Moghalu ti ṣiṣẹ́ rí ní United Nations láti ọdún 1992 sí 2008. Ó ti ṣe igbá-kejì gómìnà Ilé Ìfowópamọ́ Àgbà ti Nàìjíríà láti ọdún 2009 sí 2014, níbi tí “ó ti tukọ̀ ọ àwọn àgbà iṣẹ́ àtúnṣe nínú ètò ìkówóoamọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lẹ́yìn ìgbà tí ọrọ̀ Ajé àgbáyé ti ṣe òjòjò tán.” Òun ni òǹdíje ní abẹ́ àsíá Ẹgbẹ́ Olóṣèlú Ìtẹ̀síwájú Ọ̀dọ́ – YPP. Omoyele Sowore Sowore ni olùdásílẹ̀ àti atẹ̀wéjáde SaharaReporters , ilé-iṣẹ́ oníròyìn aṣèwádìí orí-ayélujára. SR ni à ń pè ní Wikileaks Ilé Adúláwọ̀. Ajà-fún-ẹ̀tọ́-ọmọnìyàn yìí ń jáde lábẹ́ àsíá African Action Congress. Aré ti ń lọ fún ọjọ́ iwájú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà Buhari àti Abubakar ni afigagbága ìdíje ìbò aré yìí. Àwọn méjèèjì ti ń figagbága nínú ìbò Nàìjíríà ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́. Ní ọ̀nà kejì, Ezekwesili, Moghalu, Sowore, àwọn “agbára ìkẹ́ta”, jẹ́ ẹgbẹ́ tí ó ń wọ inú ètò ìṣèlú fún ìgbà àkọ́kọ́. Iṣẹ́ ìṣàkóso Buhari ọdún mẹ́ta ni yóò “gbè é” lẹ́yìn àti pé yóò bá ìfi Nàìjíríà sí ipò olú orílẹ̀-èdè tí ìṣẹ́ ti pọ̀ jù. Ìwé ìròyìn Punch ṣe ìfojúsùn “ìpèsípò” gẹ́gẹ́ bí “àìròtẹ́lẹ̀ ” àti pé ó ti pín ìlú yẹ́bẹyẹ̀bẹ. Ètò ìgbógunti ìwà àjẹbánu rẹ̀ fì sí ẹ̀gbẹ́ kan. Ìgbésẹ̀ tí ó gbé láì pẹ́ yìí láti ṣe ìgbẹ́jọ́ Adájọ́ Àgbà orílẹ̀ èdè tí ó ti sún mọ́ ìbò ààrẹ ni Àjọ Adájọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà Nigerian Bar Association pè ní “àwòṣe ìkọlù ní lemọ́lemọ́ ní orí àwọn àgbà ẹ̀ka ìjọba méjèèjì tí-kò-gbáralé ìjọba” ní abẹ́ ìṣàkóso Buhari. Abubakar, ní ọ̀nà kejì, ń dúró lórí “ìgbẹ́kẹ̀lé” àwọn “ẹgbẹlẹmùkù okòwò tí ó ní èrè lóríi rẹ̀”. Bíótiwùkíórí, ó ní láti bá agbára ìwàlóríoyè afigagbága rẹ̀ takọ̀ngbọ̀n. Ẹni yòówù tí ó bá gbégbá-orókè nínú ìdíje sí ipò ààrẹ ọdún 2019 ní iṣẹ́ ìmúgbòòrò ọrọ̀ Ajé, ààbò ní àárín ìlú, àtúntò agbára àti ìmúkárí agbára, àti ìṣèlú elẹ́yàmẹyà làti ṣe. ‘Ẹ Yé é Pa Àwọn Òbìnrin’ – ìpolongo tuntun tí ó ń tako ìjìyà inú ìgbéyàwó ní Angola Nígbà tí wọ́n bá òkú agbẹjọ́rò tí ó jẹ́ ẹni ọdún 26, Carolina Joaquim de Sousa da Silva nínú ilée rẹ̀ ní ọjọ́ 3, oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2018, ọkọ rẹ̀ jẹ́wọ́ ọ̀ràn náà, ó sì di èrò àhámọ̀ ẹ̀ka tí ó ń ṣe ìwádìí ìwà ọ̀daràn ti Angola tí a mọ̀ sí SIC. Láàárín ọ̀sẹ̀ kan náà, ìròyìn ikú obìnrin kan ni ó jáde láti ilé-iṣẹ́ Amóhùn-máwòrán Gbogboògbò orílẹ̀-èdè Angola tí ó ní wípé ọ̀rẹ́kùnrin ìgbà-kan-rí obìnrin náà ni ó gún un pa. Àwọn ọ̀ràn ìwà ọ̀darànmọràn yìí ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin ní orílẹ̀-èdè Angola dúró gírígírí, èyí sì fa ìpolongo tuntun kan tí ó ń tako ìjìyà abẹ́lé tí wọ́n pe àkóríi rẹ̀ ní “Ẹ Yé é Pa àwọn Obìnrin” tí Ẹgbẹ́ Ondjango tí ó jẹ́ àjọ ajàfúnẹ̀tọ́ obìnrin tí kì í ṣe ti ìjọba ṣe àgbékalẹ̀ẹ rẹ̀. Wọ́n ṣe àmúlò Facebook gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìkórajọ wọn, èròńgbà wọn ni láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ nípa àwọn ìjìyà obìnrin ní orílẹ̀-èdè Angola: Àsìkò yìí jẹ́ èyí tí ó le. Lóòótọ́, fún àwa obìnrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ni ó le tí ó sì ń dùn èèyàn nítorí pé a ṣì wà ní ipò tí ó jẹ́ pé a máa ń yẹra fún ìjìyà lọ́nà kan tàbí òmíràn. Láìpẹ́ yìí gan-an pàápàá, ó dunni láti máa kojú àwọn ìhùwàsí tí ó ń jáde lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ti Carolina… Lóòótọ́ ni ìjìyà àwọn obìnrin, ó wà lóòótọ́. Kì í ṣe ohun tí ó kàn wá lórí àwọn ajàfúnẹ̀tọ́ obìnrin, kì í sì í ṣe ọ̀rọ̀ àgbélẹ̀rọ tàbí ọ̀rọ̀ òfìfo, LÓÒÓTỌ́ NI! Ó ṣeni láàánú pé ti Carolina kún ìṣirò tí ó ti wà nílẹ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀ràn báyìí ti wáyé kí tirẹ̀ ó tó ṣẹlẹ̀ tí àwọn ènìyàn gbọ́ sí, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀ràn mìíràn tí àwọn èèyàn ò mọ̀ sí, ó jẹ́ ìṣòro kan tí ó ti wà níbẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà níwájú wa. Ó sì jẹ́ ìṣòro tí ó ń ro ti ìbáṣe láàárín tọkọtaya – ìṣòro àtilẹ̀wá ni. Ètò ìpìlẹ̀ kan wà tí ó ń pàṣẹ tí ó sì ń rẹ àwọn obìnrin sílẹ̀ sí ipò ẹ̀yìn tí èyí sì sọ wọ́n di olùfaragbá ìjìyà lóríṣiríṣi àti ní gbogbo ọ̀nà. Ètò fífi akọ ṣe olórí yìí tí ó ti kọ́ wa lọ́rùn tipẹ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ń kọ̀ pé kò rí bẹ́ẹ̀ – ìyẹn kò sì ṣe é rí – ohun tí ó ń ṣe rè é: ó ń sọni di aláàbọ̀-ara, ó ń ba ayé àwọn obìnrin jẹ́, bẹ́ẹ̀ ló ń pani. Àwa obìnrin lọ́kọ̀ọ̀kan àti àpapọ̀ọ wa, a máa tẹ̀síwajú láti máa pariwo kí ‘ẹ yéé pa wá’ kí ẹ sì ‘yéé ṣe wá léṣe’. À ń fẹ́ àwọn òfin tí yóò dáàbò bò wá tí wọn yóò sì kún ojú ìwọ̀n, a fẹ́ àwọn ètò àmúlò gbogboògbò tí yóò mú àpọ́nlé wa lọ sí àwọn ìtàkùrọ̀sọ àti àwọn ìdásílẹ̀. A fẹ́ àwùjọ tí ẹ̀rù àtijáde ò ti ní bà wá! A máa tẹ̀síwajú láti béèrè fún àwùjọ tí a óò ti ní òmìnira ti ara, òmìnira ìmọ̀lára, òmìnira ìrìn àti òmìnira ríronú bí a ṣe fẹ́. A máa tẹ̀síwajú láti béèrè fún àwùjọ tí a ti lè gbáyé pẹ̀lú ààbò tó péye. Bẹ́ẹ̀, ìpolongo yìí mú èsì tí ó ń takoni wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n rí ìdí fún ìdáláre fún ìrúkèrúdò fífi ìyà jẹ obìnrin. Wọ́n pe ìpolongo wọn ní “Ẹ Yé é Dà Wá”, wọ́n gbà pé ìwà ọ̀dàlẹ̀ jẹ́ ìdí tí ó tọ́ láti máa fìyà jẹ obìnrin. Bíótilẹ̀jẹ́pé èrò wọn ò tí ì máa rinlẹ̀, Olórin Angola, Gill Slows Allen Russell náà sọ̀rọ̀; “Ẹ yé é da ẹlòmíràn, ẹ jọ̀wọ́ a ò fẹ́ aláìṣòdodo aya mọ́. À ń ké tantan, ẹ̀yin obìnrin bí ẹ kò bá nífẹ̀ẹ́ wa mọ́, ẹ béèrè fún ìtúká kí ẹ tó máa dà wa, ẹ máa lọ. Onímọ̀ àwùjọ Mbangula Kemba sọ̀rọ̀ tako ojú tí wọ́n fi wo ọ̀rọ̀ yìí, ó tẹnumọ́ọ pé wọn ò gbọdọ̀ fi ìfìyàjẹni yanjú ìṣòro nínú ìgbéyàwó. Angola fi ìdí òfin tí ó ń de ìfìyàjẹni tí wọ́n mọ̀ sí múlẹ̀ ní ọdún 2011 tí ó ń sọ onírúurú ìfìyàjẹni abẹ́lé di ìwà ọ̀daràn ní gbangba. Síbẹ̀síbẹ̀, ìdájọ́ òfin yìí kò le tó, ìtìmọ́lé ọdún méjì sí mẹ́jọ. Sizaltina Cutaia, tí í ṣe ajìjàǹgbara àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin ní Angola; tí ó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká fún iṣẹ́ẹ rẹ̀ lórí ẹ̀tọ́ obìnrin béèrè fún ìṣàmúlò òfin náà lórí àwọn gbàgede ìtàkùrọ̀sọ lórí ẹ̀rọ-alátagbà: Àfikún ọdún ẹ̀wọ̀n kò tó, arábìnrin igbá-kejì Ààrẹ MPLA [Àjọ Àwọn ènìyàn tó fẹ́ ìdásílẹ̀ Angola], Ó nílò kí orílẹ̀-èdè ṣe ìdásílẹ̀ àwọn ìlànà àtilẹ̀wá tí yóò kojú ìpanilára – Àwọn ohun tí wọ́n fara mọ́ ní 2007 nípa àjọsọ ìlànà Maputo ní láti di ṣíṣe. Bákan náà ni ti èyí, ó nílò kí wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ òfin arọ́pò tí yóò mú ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin rinlẹ̀. Lára èyí ni gbogbo òfin tí ó de obìnrin ní ti ìbálòpọ̀ àti ẹ̀tọ́ ọmọ bíbí wà. Kò sí ìwúlò ìsọ̀rọ̀ tako ìjìyà abẹ́lé kí ó wá di ẹ̀yìn wá kí a máa ṣe ìgbèlẹ́yìn àwọn òfin tí ó fi àṣẹ fún agbófinró láti yẹ̀yẹ́ obìrin ní títì ní ojúmọ́, kò bá ara mu! Kò wúlò kí a máa sọ̀rọ̀ tako ìjìyà abẹ́lé kí a sì tún máa gbèlẹ́yìn àṣàrò ìnáwó tí kò ní ṣe ààbò ètò àwùjọ, ìṣúná àìtó tí gbogbo wa mọ̀ pé ipa òdì ni ó ń kó nínú ayé àwọn obìnrin. Ó ṣe pàtàkì kí a fi ọgbọ́n kún àwọn ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ṣíṣe gidi. Ẹ fi owó yín sí ibi tí ẹnu yín wà. Ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin Cecelia Kitombé sọ̀rọ̀ sí àwọn tí ó ń ṣe àtìlẹyìn ìbáṣepọ̀ tí ó níyà nínú: Lára wa tí à ń tẹnumọ́ ọn pé ó pọ̀jù [láti sọ̀rọ̀ síta tako ìjìyà Abẹ́lé] náà ni ẹni tí ó ń gba àwọn ọmọbìnrin, arábìnrin àti ìbátan lóbìnrin níyànjú láti máa fi ara da ìbáṣepọ̀ tí ó ń pani lára pẹ̀lú ọ̀rọ̀-ẹ̀tàn pé ọ̀rọ̀ tọkọtaya ò ṣe é dá sí, àwọn mìíràn á ní kí o tẹ̀síwajú bẹ́ẹ̀, bí ọ̀rọ̀ lọ́kọláya ṣe rí nìyẹn… Àwọn kan tilẹ̀ rò pé obìnrin lè ṣe gbogbo nǹkan, ṣùgbọ́n wọn ò gbọdọ̀ gbàgbé ‘ojúṣe’ wọn. Ẹ yéé pa wá!!! Ìjàm̀bá Àwọn Ológun Mauritania 28 tí wọ́n pa ní ọjọ́ Òmìnira tí a kò sọ Ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Belu ọdún 1990, àwọn ẹgbẹ́ ológun yẹgi fún ọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n tí a fi ìfarabalẹ̀ ṣà lọ́kọ̀ọ̀kan láti pa nínú ẹ̀wọ̀n láàárín òru, ní Inal ní orílẹ̀-èdè Mauritania lẹ́yìn tí a fi ẹ̀sùn ìpète-lati-gba-ìjọba kàn wọ́n. Ọjọ́ yìí, tún jẹ́ àyájọ́ ọjọ́ tí orílẹ̀-èdè Mauritania gba òmìnira lọ́wọ́ France ní ọdún 1960, lé góńgó sọ́kàn àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Mauritania kan tí wọ́n ń wá ìdájọ́ òdodo fún ìpakúpa tí wọ́n pa àwọn ọkùnrin 28 yìí, tí gbogbo wọn sì jẹ́ aláwọ̀ dúdú. Orílẹ̀-èdè Mauritania ti Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀ jẹ́ ìdàpọ̀ àwọn Lárúbáwá àti àwọn aláwọ̀ dúdú, àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn sọ pé àwọn aláwọ̀ dúdú ti ń dojúkọ ìyàsọ́tọ̀ àti ìlòkulò fún ìgbà pípẹ́. Ààrẹ Ìgbìmọ̀ àwọn Inal-France, Youba Dianka, ṣàlàyé: Mo fẹ́ fi hàn wípé àpẹẹrẹ ni Inal jẹ́; ọ̀pọ̀ ọmọ ‘Inal’ ni ó ti wà ní Mauritania. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abanilẹ́rù ti w��yé ní Azlatt, Sony Malé, Wothie, Walata, Jreida àti nínú àfonífojì. Nínú ọgbà àwọn ológun ní Inal àti àgbègbè rẹ̀, wọ́n pín àwọn ológun yẹ́lẹyẹ̀lẹ, wọ́n rì wọ́n mọ́lẹ̀ ní òòyẹ̀, wọ́n yìnbọn lù wọ́n, wọ́n sì yẹgi fún wọn ní ìrántí òmìnira orílẹ̀-èdè náà lọ́dún 1990. Ní àyájọ́ ọjọ́ òmìnira ti ọdún yìí, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Mauritania fi ọkàn sí yíyàn tí a yan ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè wọn sí àṣekágbá ìdíje Ife-ẹ̀yẹ ti àwọn orílẹ̀-èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ (CAF) ju bí wọ́n ṣe ṣe sí àwọn ẹni ìgbàgbé, “àwọn ológun tí wọ́n wà nínú kòtò àìmọ̀… tí wọ́n ṣì ń dúró de ìsìnkú tí ó yẹni“, Kaaw Elimane Bilbassi Toure tí í ṣe olóòtú ibùdó ìròyìn orí ayélujára Le Flambeau ti Mauritania kọ. Kiné-Fatim Diop, adarí ìpolongo Amnesty International ní Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀, sọ̀rọ̀ ní ọdún yìí nípa ìtakora tí ó wà ní àárín ohun tí ó yẹ kí ó jẹ́ ọjọ́ ìṣèrántí-dunnú àti ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbí àwọn olùfarapa ń rò: Lọ́dọọdún, bí àwọn tí wọ́n dipò mú ṣe ń ṣe ìrántí ìgùnkè wọn sí ipò gíga pẹ̀lú ìdùnnú, ẹbí àwọn olùfarapa máa ń sunkún, tí wọ́n sì máa ń fi ẹhónú hàn pẹ̀lú ìbànújẹ́ fún àtúnṣe àti ìdájọ́ òdodo. Àwọn tí ó wà nípò àṣẹ kàn ń gbìyànjú láti ri apá òmìnira tí kò farahàn yìí mọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe dìbò yan òfin ìdáríjì ìjọba ní ìkọ̀kọ̀ lọ́dún 1993 tí wọ́n sì fìdí ìgbàgbé ìjọba múlẹ̀ nípa ìpakúpa àwọn ológun náà lọ́gbọ̀n ọdún sẹ́yìn. Àjọ tí ó ń tako àìjìyà ẹlẹ́ṣẹ̀ àti àìṣòdodo ní orílẹ̀-èdè Mauritania Forum Against Impunity and Injustice fi ìbànújẹ́ hàn lórí ìjàm̀bá àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò kan tí a yẹgi fún lálẹ́ ọjọ́ burúkú Èṣù gb'omi mu yìí. Láìsí àní-àní, èpè ja àwọn ológun 28 yẹn lóru ọjọ́ náà. Bí i ti àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, Diallo Oumar Demba àti àbúròo rẹ̀ Diallo Ibrahima tí a yẹgi fún pẹ̀lú àkọsílẹ̀ nọ́ḿbà tí ó tẹ̀lé ara wọn tí a fi gègé kọ sí wọn lára. Ohun tí ó mú èyí bani nínú jẹ́ jù ni fún ẹni láti rí ikú tí ó pa ẹ̀gbọ́n ẹni. Àwọn apani ṣe iṣẹ́ wọn pé, wọn kò sì dáwọ́ dúró lẹ́yìn tí wọ́n yẹgi fún wọn, wọ́n tún wọ́ òkúu wọn nílẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sì ń jókòó lé wọn lórí. Àwọn Ẹni-orí-kó-yọ sọ̀rọ̀ síta Ẹ̀rí túbọ̀ ń tẹnu àwọn ẹni-orí-kó-yọ jáde lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún. Mamadou Sy jẹ́ apàṣẹ ẹgbẹ́-ológun nínú ẹgbẹ́ ológun Mauritania, ó ti jẹ́ igbákejì apàṣẹ, kí ó tó wá di apàṣẹ ẹgbẹ́ ológun ẹ̀ka kan kí wọ́n tó mú un ní alẹ́ ọjọ́ yẹn. Nínú ìwée rẹ̀, “Ọ̀run-àpáàdì ní Inal“, tí a tẹ̀ jáde ní ọdún 2000, ó ṣàpèjúwe ìjìyà-oró tí ó jẹ, nígbà tí àwọn apàṣẹ ológun dì í lójú, so ó mọ́lẹ̀, tí wọ́n sì jù ú sínú omi ìdọ̀tí rírùn. Ológun mìíràn tí orí kó yọ lálẹ́ ọjọ́ burúkú yìí tiraka gba France lọ fún ìtọ́jú lẹ́yìn tí ó kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn Àjọ Onígbàgbọ́ tí ó ń tako Ìfìyàjẹni (ACAT lédè Faransé). Ní ipò àìlórúkọ, ó jẹ́rìí sí ìyàsọ́tọ̀ ẹ̀yà tí ó rí láàárín ọdún mẹ́rìnlélógún tí ó fi ṣiṣẹ́ ológun: Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe rántí, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í yé mi, mo ti máa ń ṣàkíyèsí pé àwọn aláwọ̀ dúdú kì í ní ẹ̀tọ́ kankan, ṣùgbọ́n àwọn aláwọ̀ funfun ará Mauritania máa ń ní àǹfààní tí ó pọ̀. Níbí, nínú ogún àwọn adarí ipò ìjọba, ìdá mẹ́rin péré ni wọ́n jẹ́ aláwọ̀ dúdú. Nínú ẹgbẹ́ ológun, aláwọ̀ dúdú kan ṣoṣo ni ó máa ń wà láàárín ológun mẹ́wàá. Nígbà ìkọ́ṣẹ́, bí ọmọ Mauritania aláwọ̀ funfun kan kò bá ṣe dáadáa, wọn á ṣì borí aláwọ̀ dúdú mìíràn. A ò sì gbọdọ̀ fi ẹhónú hàn… Ó ṣe àpèjúwe àwọn ìfìyàorójẹni tí òun pẹ̀lú àwọn ológun mìíràn rí: Fún àpẹẹrẹ, wọ́n gbẹ́ kòtò sínú iyẹ̀pẹ̀, wọ́n sì rì wá mọ́lẹ̀ dé ibi ọrùn, orí wa ò ṣe é yí, ojú wa sì wà ní ìhà oòrùn. Tí a bá sì gbìyànjú láti pa ojú dé, àwọn ẹ̀ṣọ́ á da iyẹ̀pẹ̀ sí wa. Wọ́n á sì wọ ìbòjú padà. Maimouna Alpha Sy, akọ̀wé gbogboògbò fún Ẹgbẹ́ Ọ̀ràn Opó àti Aṣàánù ọmọ-ènìyàn, ti fi ìgbà kan rí jẹ́ aya Ba Baïdy Alassane, tí ó jẹ́ adarí àwọn ẹ̀���ọ́ ibodè tẹ́lẹ̀. Alpha Sy sọ pé ọkọ rẹ̀ tí ó ti di olóògbé wà lára àwọn tí wọ́n pa lọ́dún 1990. Oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ni a fi wá ọkọ mi, ṣùgbọ́n pàbó ni ó já sí… Àwọn ẹ̀ṣọ́-ibodè sọ fún wa pé àìsàn ọkàn ló pa á, tí èyí kò sì jẹ́ òtítọ́. Wọ́n mú àwọn tó jẹ́rìí pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n so wọ́n, wọ́n sì fi ìyà oró jẹ wọ́n pẹ̀lú rẹ̀. Ní iwájú wọn ni wọ́n ti pa á. ‘Kò tún gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ mọ́’ Lọ́dún yìí ni ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, àwọn ọmọ Mauritania tí wọ́n jẹ́ aṣíkiri fi ẹ̀hónú hàn níwájú Ẹ́mbásì Mauritania ní ìlú Paris, ní orílẹ̀-èdè France, lórí àìfiyèsí ìjọba nípa ìṣẹ̀lẹ̀ oró yìí. Kardiata Malick Diallo, tí ó jẹ́ igbákejì, sọ ọrọ àròjinlẹ̀ ní ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin Mauritania láti máà jẹ́ kí àwọn ènìyàn gbàgbé, tí ó sì fi ẹ̀sùn kàn ààrẹ tí ó wà lórí oyè pé ó ń dáàbò bo àwọn oníṣẹ́-ibi náà, tí wọ́n ṣì ń dipò gíga mú nínú ìjọba nígbà tí wọn kò tí ì wá nǹkan ṣe sí ẹ̀tọ́ àwọn olùfarapa: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kọ́ ni o ṣe iṣẹ́-ibi tí ó kó àbààwọ́n ba gbogbo ọjọ́ 28 oṣù Belu jẹ́, ìwọ ni ó yẹ kí o wá ojútùú sí ẹ̀tọ́ àwọn olùfarapa sí òtítọ́ àti òdodo… Àwọn orílẹ̀-èdè olókìkí àti àwọn èèyàn ńlá kì í gbìyànjú láti pa ìṣẹ̀lẹ̀ aburú inú ìtàn-an wọn rẹ́, dípò èyí wọ́n máa ń fi han ayé kí gbogbo ènìyàn lè rántí kí wọ́n sì sọ pé “KÒ TÚN GBỌDỌ̀ ṢẸLẸ̀ MỌ́’. Ọ̀gbẹ́ni ààrẹ, àkósoò rẹ ti ṣe àmúlò òfin ìyàsọ́tọ̀ àti ìyọkúrò ẹ̀yà. Ní oṣù Ọ̀wàrà ọdún 2018, nínú àwọn adarí ipò ìjọba 24, márùn-ún péré ni àwọn tí ó jẹ́ aláwọ̀ dúdú àti elẹ́yà-méjì, tí wọ́n ń ṣojú ìdá 70 àwọn mẹ̀kúnù. Ọ̀pọ̀ àwọn mẹ̀kúnù ni wọ́n kò ní aṣojú láàárín àwọn aṣojú tí wọ́n dìbò yàn, láàárín àwọn ẹgbẹ́ àbò àti àwọn adarí ipò ìjọba ìbílẹ̀. Mauritania ni orílẹ̀-èdè tí ó gbẹ́yìn láti pa òwò-ẹrú rẹ ní àgbáyé ní ọdún 1981, ṣùgbọ́n wọn kò fi ìdíi rẹ̀ múlẹ̀ títí di ọdún 2007, ìdá 20 àwọn ènìyàn ni wọ́n ṣì ń gbáyé ìṣẹrúsìn tí púpọ̀ nínú wọn sì jẹ́ aláwọ̀ dúdú tàbí elẹ́yà-méjì. Nítorí ìyàsọ́tọ̀ ẹ̀yà yìí ṣì ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Mauritania, ìdájọ́ òdodo kò sí ní àrọ́wọ́tó fún àwọn ẹni orí-kó-yọ àti àwọn ìdílé wọn. Kí ló dé tí ìjọba Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ń f'òfin de ọ̀rọ̀ sísọ orí-ayélujára? Nítorí wọ́n bẹ̀rù agbára rẹ̀. Ọ̀rọ̀ sísọ lórí ayélujára ti ń rí ìfúnpa láti ọwọ́ ìjọba díẹ̀ díẹ̀. Nínú ìlànà òfin àti ọ̀rọ̀ Ajé, iye òmìnira ọ̀rọ̀ ń dìde kárí Ilẹ̀-Adúláwọ̀. Nígbà tí àwọn ìjọba kan mọ rírì ètò ìjọba àwa-arawa nípasẹ̀ ṣíṣe ìbò pẹ̀lú ọlọ́pọ̀-ẹgbẹ́ òṣèlú àti sọ nígbangba nípa àjọṣe, nínú ìṣe, ọ̀pọ̀ máa ń lo àṣẹ tí ò ṣe é yí padà wọ́n sì ń lo agbára àṣẹ yìí lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá bí ọjọ́ ṣe ń gun orí ọjọ́. Cameroon, Tanzania, Uganda, Ethiopia, Nigeria, àti Benin ti ní Ìtìpa Ẹ̀rọ-ayélujára, ìjọba ti fi owó-orí lé lílo búlọ́ọ̀gù àti ẹ̀rọ-alátagbà, wọ́n sì ti fi ọwọ́ ṣìgún òfin mú oníròyìn. Òṣìṣẹ́ ìròyìn àti àwọn ọmọ-ìlú ti di èrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn àtẹ̀jáde “ìròyìn irọ́” títí kan ìkóròyìn ìkòkọ̀ ìlú sí etí ìgbọ́ ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò. Ní ibi Àpérò Òmìnira Ẹ̀rọ-ayélujára ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ (FIFA) tí ó wáyé ní Accra, Ghana, ikọ̀ akópa láti àwọn ìlú ilẹ̀ Adúláwọ̀ pátá sọ wípé kò ní ṣe ẹnu rere bí ìjọba bá fi òfin de ọmọ-ìlú tí ó ń lo ẹ̀rọ-ayárabíaṣá. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ní àwọn òfin àti àbádòfin tí ó fún ọmọ ènìyàn ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Ní Nàìjíríà, fún àpẹẹrẹ, Àbádòfin Òmìnira Ọ̀rọ̀ fún ọmọ ìlú ní òmìnira láti béèrè fún ìwífun lọ́wọ́ àjọ ìjọba. Abala 22 ìwé òfin ọdún 1999 pèsè fún ẹ̀tọ́ òmìnira ìròyìn àti Abala 39 fi lélẹ̀ wípé “gbogbo ènìyàn ni ó ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, títí kan òmìnira láti gbá ìròyìn mú àti gba ọgbọ́n àti ìwífun láì sí ìdíwọ́…” Síbẹ̀, Nàìjíríà tí tẹ àwọn òfin kan tí ó tẹ orí àwọn ẹ̀tọ́ òkè yìí bọlẹ̀. Abala 24 Òfin Ẹ̀ṣẹ̀ orí-ayélujára fi ẹ̀sùn kan “ẹnikẹ́ni tí ó bá tan iṣẹ́-ìjẹ́ tí kò ní òótọ́ kan nínú, tí ó lè fa ìbínú, ìnira, ewu, ìdíwọ́, àfojúdi, ìdáyàfò ọ̀daràn, ọ̀tá, ìkórìíra, tàbí ìbínú láì ní ìdí sí ẹlòmíràn ká tàbí fa kí a fi irúfẹ́ iṣẹ́-ìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́.” Ìṣòfin àìdájú àti àwọn gbólóhùn bíi “ìnira” tàbí “ìwọ̀sí” jẹ́ nǹkan tí a ní láti mójútó. Ìjọba àti àwọn àjọ rẹ̀ máa ń sábà fi èyí ṣe bójúbójú fún ìtẹríbọlẹ̀ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Ta ni ẹni tí ó ń sọ bóyá ọ̀rọ̀ kan jẹ́ àfojúdi? Ǹjẹ́ ó yẹ kí òṣìṣẹ́ ìjọba ó ṣe ìmúdàgbà àwọ̀-ara tí ó ní ipọn? Ní àgbáyé, ọmọ-ìlú ní ẹ̀tọ́ láti wá àìṣedéédé aláṣẹ ìjọba. Kí ló dé tí Ilẹ̀-Adúláwọ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka tí ó ṣe pàtàkì nínú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ? Ní ọdún 2017 àti 2016, oníròyìn orí-ayélujára ọmọ bíbí ìlú Nàìjíríà àti akọbúlọ́ọ̀gù Abubakar Sidiq Usman àti Kẹ́mi Olúnlọ́yọ̀ọ́ tí ta ẹsẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin nípasẹ̀ ṣíṣe iṣẹ́ ìkóròyìnjọ lóríi Òfin Ẹ̀ṣẹ̀ orí-ayélujára. Máà jìyà nínú ìdákẹ́rọrọ máa wí lọ Ìwà tí ó jẹ́ gbòògì àwọn ìpèníjà wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bíi ti òfin ń sọ fún ọmọ-ìlú pé ohùn-un wọn ṣe kókó. Kí a mú un láti Ìdádúró Tanzania tí ó dá lóríi ìtànká “ìròyìn irọ́, ìtànjẹ, tàbí ìròyìn tí ò pé ojú òṣùwọ̀n” lórí ayélujára títí kan owó-orí Uganda fún ìlò ẹ̀rọ-alátagbà fún ìgbógunti “àhesọ”, ariwo orí ẹ̀rọ-ayárabíaṣá ń já àwọn ìjọba aninilára láyà. Ní ìgbà mìíràn, ó máa mú wọn pa àwọn ìwàa wọn tì. Ìrírí akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 ìlú Ethiopia jẹ́ àpẹẹrẹ. Ní ọdún 2014, àwọn òǹkọ̀wé ọmọ bíbí Ethiopia mẹ́sàn-án lọ sí ẹ̀wọ̀n àti jìyà oró látàrí iṣẹ́ àjọṣepọ̀ tí wọ́n jọ kọ nípa ìtẹsẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí ẹ̀tọ́ ọmọ-ènìyàn ìjọba àná ìlú Ethiopia, kí òótọ́ ó di mímọ̀. Ìjọba pe ẹgbẹ́ yìí ni “afẹ̀míṣòfò” nítorí àtẹ̀jáde orí ẹ̀rọ-ayélujára wọn a sì ti wọ́n mọ́lé fún oṣù 18. Àwọn mẹ́fà lára àwọn ẹgbẹ́ náà tí ó ti gba òmìnira báyìí ṣe ìtàkùrọ̀sọ àgbáyé àkọ́kọ́ ní ìlú Ghana ní àsìkò àpérò FIFA: Atnaf Berhane, Befeqadu Hailu Techane, Zelalem Kibret, Natnael Feleke Aberra, àti Abel Wabella náà wá sí àpérò. Jomanex Kasaye, ẹni tí ó ti bá ẹgbẹ́ náà ṣiṣẹ́ kí àtìmọ́lé ó tó ṣẹlẹ̀ (àmọ́ tí a kò fi àṣẹ mú) náà kò gbẹ́yìn níbi àpérò. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ẹgbẹ́ yìí ti bá Ohùn Àgbáyé ṣe pọ̀ láti kọ àti ṣe ìtúmọ̀ ìròyìn sí èdè Amharic. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé ṣe ìpolongo àti ìpanupọ̀ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àgbáyé gẹ́gẹ́ bi agbẹnusọ láti ọjọ́ tí wọ́n dé akoto ọba. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tí a tẹ ọ̀kanòjọ̀kan ìròyìn jáde àti ìgbélárugẹ ìtàkùrọ̀sọ ọ̀ràn wọn lórí Twitter, ìdálébi ìfàṣẹmú àti àtìmọ́lé gba ojúlé ìjọba àti àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní àgbáyé kọjá, láì gbàgbé àwọn ọgọọ́gọ̀rún àti ẹgbẹẹ̀gbẹ̀rún alátìlẹ́yìn orí ẹ̀rọ-ayélujára. Láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé, igbe ńlá ni ó gba àwọn akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 sílẹ̀ lọ́wọ́ ìjọba ilẹ̀ Ethiopia. Nínú ọ̀rọ̀ wọn ní FIFA, àwọn akọbúlọ́ọ̀gù náà sọ wípé ìkẹ́gbẹ́ẹ wọn nínú Ohùn Àgbáyé ṣe gudugudu méje yàyà mẹ́fà ní àsìkò tí àwọn ń fi aṣọ pénpé ro oko ọba. Ní ètò ìtàkùrọ̀sọ wọn, wọ́n gbé orí yìn fún ìpolongo Ohùn Àgbáyé tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi tí ó mú àwọn wà láyé. Berhan Taye, atọ́kùn ìtàkùrọ̀sọ, bi ẹgbẹ́ yìí ní ìbéèrè ìrírí wọn ní inú túbú. Bí wọ́n ti ṣe sọ, iná amọ́roro ìtàgé wálẹ̀ díẹ̀. Ohùn-un wọn mú kí iyàrá ètò pa lọ́lọ́. Abel Wabella, alákòóso Ohùn Àgbáyé ní ‘ Èdè Amharic , kò fi etí ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ kan gbọ́ràn já geere mọ́n láti ara ìjìyà oró tí ó jẹ́ nítorí pé ó kọ̀ láti ti ọwọ́ bọ ìwé ìjẹ́wọ́. Atnaf Berhane rántí wípé òún jẹ ìyà oró di aago méjì òru tí òún padà sí lẹ́yìn oorun díẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn agbófinró tí ó mú Zelalem Kibret ti fi ìgbà kan rí jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Kibret ní Ifásitì tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ olùkọ́. Jomanex Kasaye náà ṣe ìrántí ìwàyáìj�� ọpọlọ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìrònú ìfìlú Ethiopia sílẹ̀ kí wọ́n ó tó fi ọwọ́ òfin mú àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀ ìrora àìlágbára ìlàkàkà ọkàn àti àìfẹ̀dọ̀lórí òróòró àti ìbẹ̀rù wípé àwọn ọ̀rẹ́ òhun ò ní jáde láàyè. Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, àwọn akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 sọ wípé: “A kò kí ń ṣe ẹni tí ó ní okun tàbí ìgboyà.. inúu wa dùn nítorí wípé a fún àwọn ènìyàn mìíràn ní ìmísí ni.” Síbẹ̀, akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 ṣe àtúnlò ìfẹ́-ìlú-ẹni nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Ó gba ìgboyà láti fẹ́ràn ìlú ẹni pàápàá lẹ́yìn ìjìyà nítorí wípé a sọ̀rọ̀ síta. Oníròyìn ọmọ Uganda Charles Onyango-Obbo, tí òun náà wà ní FIFA, mẹ́nu ba òwe Igbo tí gbajúgbajà òǹkọ̀wée nì Chinua Achebe mú di mímọ́ tí ó sọ wípé: Níwọ̀n ìgbà tí òde ti já ọgbọ́n àtamátàsè, ẹyẹ Eneke náà ti kọ́ fífò láì bà. Ní àkótán, ohun tí ó fẹ́ sọ ní wípé láti mú ayélujára wà ní ipò ọ̀fẹ́ àti ààbò, àwọn tí ó ń jà fún èyí nílò láti wá ọgbọ́n mìíràn dá. Àwọn ajàfúnẹ̀tọ́ tí ó ń lé iwájú nínú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní ìlú-Gúúsù-Aṣálẹ̀-Sàhárà àti káríayé kò gbọdọ̀ ṣe aláì máà wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣ'àdá lórí ọ̀ràn yìí. Pẹ̀lú agbára àti àjọṣe wa, ẹ̀rọ-ayélujára yóò di ibi òmìnira fún ìtẹ̀síwájú ìjọba àwa-arawa. Òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ òfuurufú olóbìrin nìkan wọ ìwé ìtàn ní Mozambique Ọjọ́ ìtàn ni ọjọ́ yìí: ojú yìí ni ogunlọ́gọ̀ ọmọ-ìlú Mozambique fi wo ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ 14, oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2018 nígbà tí, fún ìgbà àkókọ́ nínú ìtàn ìgbésí ayé ètò ọkọ̀ òfuurufú ìlú náà, tí obìnrin jẹ́ atukọ̀. Ikọ̀ bàlúù TM112/3, tí ó rin ìrìn àjò láti olú ìlú, Maputo, àti Manica tí jíjìn sí ara wọn tó máìlì 442 ni a tí rí atukọ̀ Admira António, atukọ̀ kejì Elsa Balate, olóyè ọkọ̀ Maria da Luz Aurélio, àti òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ Débora Madeleine. Àwọn obìrin wọ̀nyí wà nínú ẹgbẹ́ MEX, ilé-iṣẹ́ tí a dá sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Ẹ̀ka Iṣẹ́ Àkànṣe LAM Linhas Aéreas de Moçambique. Ní 1995, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bíi ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú aládàáni , Mozambique Express. Àtẹ̀jáde ìkíni orí Facebook láti ọwọ́ ajàfúnẹ̀tọ́ obìrin Eliana Nzualo, ti ní ìsọsí tí ó tó 450, tí a ti pín tó ìgbà 460, àti pé ọ̀pọ̀ èsì tí ó tó 2,000 ni ó gbà: ỌJỌ́ ÌTÀN – Ikọ̀ ọkọ̀ òfuurufú TM MEX kú oríire! Ikọ̀ ẹ kú oríire! Mozambique, kú oríire! Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìrin nínú iṣẹ́ gbogbo. Àjàfúnẹ̀tọ́ ìkẹ́gbẹ́ Mauro Brito sọ ní tirẹ̀ wípé obìrin gbọ́dọ̀ ní ìgbéraga “nígbàtí [wọ́n] bá jẹ́ aṣojú nínú iṣẹ́ gbogbo”: Obìrin kò pọ̀ nínú iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe rí káríayé. Mo rò ó wípé àwọn obìrin tí ó ronú láti ṣe iṣẹ́ tí ọkùnrin máa ń ṣe, gbọdọ̀ gbéraga. Mozambique nìkan kọ́. Ní oṣù Ògún ọdún 2018, nínú ọkọ̀ òfuurufú ìlú apá Gúúsù Ilẹ̀-Adúláwọ̀ SAA, ìrìnàjò ìlú dé ìlú pẹ̀lú ikọ̀ olóbìrin fò ní ojú sánmà wọ́n sì kó èrò láti Johannesburg sí Sao Paulo, Brazil. Oṣù méjìlá sẹ́yìn, ní oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2017, Ilé-iṣẹ́ Ọkọ̀ òfuurufú Ethiopia fún ìgbà àkókọ́ gbé ikọ̀ òṣìṣẹ́bìrin fò. Awọn atukọ̀ títí kan òṣìṣẹ́ gbogbo, ọkọ̀ òfuurufú láti Addis Ababa ní Ethiopia sí Èkó ní Nàìjíríà jẹ́ obìrin pátápátá porongodo. Oníròyìn Orí ẹ̀rọ-alátagbà Luis Carlos Diaz di àwátì ní Venezuela Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ 11, oṣù Ẹrẹ́nà olùfèsì sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú Naky Soto tí ó tún jẹ́ aya akọ̀ròyìn àti ajììjàǹgbara iṣẹ́ ìròyìn tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ Venezuela, Luis Carlos Díaz túwíìtì pé òun ti ń wá ọkọ òun fún wákàtí márùn-ún. [Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́] Àjọ àwọn Òṣìṣẹ́ Ìròyìn (SNTP lédè Spanish) jábọ̀ pé àwọn Agbófinró Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Bolivaria (SEBIN) ti fi Luis Carlos sí àtìmọ́lé. PÀJÁWÌRÌ Àjọ Sebin kan fìdíi rẹ̀ múlẹ̀ pé akọ̀ròyìn Luis Carlos Diaz ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá yẹn. Wọ́n yọ àwọn ohun ìjà ti akọ̀ròyìn Marco Ruiz, Luz Mely Rehes àti Federico Black [pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ìròyìn. Wákàtí díẹ̀ sẹ́yìn, Soto túwíìtì pé àwọn ti ń wá Luis Carlos Díaz fún wákàtí márùn-ún: Ẹ̀yin èèyàn àtàtà: Mi ò rí LuisCarlos bá sọ̀rọ̀ láti aago 5:30 lọ́sàn-án y��í, ó sì sọ fún mi pé òun ń bọ̀ nílé láti sinmi nítorí pé òun ní ìkéde pàtàkì kan láti se lórí Unionradionet láti aago 10:00 alẹ́ sí 5:00 ìdájí DóndeEstáLuisCarlos LuisCarlos wà ní orí kẹ̀kẹ́ẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n láti aago 5:30 ni mi kò ti gbúròó rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀: Kò sí ní ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà Kò sí nílé Kò tíì túwíìtì Kò gbé ìpèe rẹ̀ Kò fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí iṣẹ́-ìjẹ́ oríi WhatsApp [Ìròyìn tó tẹ̀wá lọ́wọ́] Luz Mely Reyes tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ojúu rẹ̀, fi tó wa létí nípa bí àwọn Agbófinró SEBIN ṣe yẹ ilée Díaz pẹ̀lú ilée Soto náà wò. Ìsọ̀kan àwọn Oníròyìn náà fẹ ọ̀rọ̀ náà lójú: NÍ KÍÁKÍÁ Ní dédé àsìkò yìí, ní dédé agogo 3:00 òwúrọ̀ kùtùkùtù, ìgbìmọ̀ láti àjọ Amúninípá dé ilé oníròyìn àti ajà-fún- ẹ̀tọ́ọ ọmọ ènìyàn Luis Carlos Díaz, tí ó ti di ẹni àwátì láti agogo 5:30 ìrọ̀lẹ́ . Àwọn ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti àjọ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ náà darapọ̀ mọ ìpolongo yìí pẹ̀lú DondeEstaLuisCarlos (Níbo ni Luis Carlos wà?), tí ó jẹ́ pé, ní báyìí, ni àkọlé tí ó gbajúmọ̀ ní orí ìkànnì ayélujára Twitter ti Orílẹ̀ Èdè Venezuela. Díaz jẹ́ ajábọ̀ ìròyìn àti a-jà-fún-ẹ̀tọ́-ọmọ ènìyàn tí ó jẹ́ ògbólógbòó ajàfúnẹ̀tọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n sì mọ ìṣe rẹ̀ fún un l'órílẹ̀ èdè Venezuela àti òkè òkun fún ìdásọ́rọ̀ àti ìtakò ìjọba Nicholas Maduro. Ó ti tó ìgbà díẹ̀ kan tí ó ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti olùdásọ́rọ̀ òṣèlú tí ó gbajúmọ̀ n nì, Naky Soto, tí wọn sì ń ṣe ìgbéjáde àwọn fídíò àti ètò Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí ayélujára èyí tí ó dá lórí ìṣèlú àti ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn ní Venezuela. Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ́ni àti olùgbé-lárúgẹ ìdásílẹ̀ àyè ọ̀tọ̀ fún àwọn ará ìlú àti àwọn àkànṣe eto ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ tí kò lọ́wọ́ ìjọ̀ba nínú. Díaz tún jẹ́ olùkópa nínú ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé fún ọdún mẹ́wàá. Lọ́dọ̀ tèmi, Luis Carlos jẹ́ onílàákàyè ẹ̀dá kan, ó gbọ́njú nínú ìròyìn gbígbà àti ìkànsì-ara-ẹni nínú Venezuela ti wa yìí tí kò fara rọ. Ó ti ṣe àwárí ìjápọ̀ nínú ìlú (láti ìtakò sí ibi ìṣẹ̀ṣe) . Láàrin ọjọ́ péréte tó ṣíwájú ìpòóráa rẹ̀, ètò ìkàn-sára- ẹni ti ìjọba Con el Mazo Dando ṣàfihàn fídíò tí Díaz sọ̀rọ̀ nínúu rẹ̀. Atọ́kùn ètò ọ̀hún, olóṣèlú Diosdado Cabello, rò kàn pé Díaz lọ́wọ́ sí ìfẹ̀hónú hàn àìsí ináa mọ̀nàmọ̀nà tí ò lọ jákèjádò orílẹ̀ èdè èyí tí ó mú kí àwọn ọmọ Venezuela máa gbé nínú òkùnkùn fún ó lé ní wákàtí mẹ́rin lé lógún lọ́jọ́ 7 àti 8 Oṣù Ẹrẹ́nà Kò sí ẹ̀rí tí ó fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀. Bí ọjọ́ ṣe ń lọ láì rí ẹ̀rí tí ó yanrantí dì mú, SNTP darapọ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ àbẹ̀wò sí olú ilé iṣẹ́ẹ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ : Wákàtí méje ti ré kọjá lọ tí Luis Carlos Díaz ti di àwátì. [Díaz] jẹ́ oníròyìn fún ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Unión Radio Noticias , ó sì tún jẹ́ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn. Àwa ní olú ilé iṣẹ́ẹ SEBIN headquarters àti pé wọ́n ní àwọn kò ní í [ní àhámọ́ àwọn] . [Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́: wọ́n pàpà jẹ́wọ́ wípé [Diaz wà ní akolóo wọn] Akọ̀ròyìn Vladimir Villegas sọ wípé kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ wípé ìjọba ni ó fi ọwọ́ agbára mú u: Olóbó ti ta wá wípé oníròyìn fún Unionradionet Luis Carlos Díaz, ti wà nínú àtìmọ́lé agbófinró Ìlú. A bá a kẹ́dùn ipò tí ó wà. A béèrè fún ìtọ́sọ́nà nípa mímọ ibi tí ó wà, àti ìbọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn-an rẹ̀. Ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé dúró ṣinṣin pẹ̀lú Luis Carlos, ẹbíi rẹ̀, àti oníròyìn aládàáṣiṣẹ́ gbogbo àwọn tí ó ń mú ìjọba ṣe bí ó ti yẹ ní Venezuela. À ń retíi rẹ̀ kí ó dé kíákíá ní àlàáfíà ara àti ẹ̀mí, a ó máa gbé àwọn ìròyìn síta nípa ìròyìn yìí bí ó ba ṣe ń tẹ̀ wá lọ́wọ́. ‘Ohùn-un Jamaica fún Àyípadà Ojú-ọjọ́’ fi orin jíṣẹ́ẹ wọn Bí orin reggae àti dancehall ṣe ń lọ ni àwọn ìpolongo tí ó ń sọ nípa ohun gbogbo láti ọṣẹ ìfọṣọ àbùfọ̀ sí oúnjẹ àsèsílẹ̀, orin ni ènìyán lè gbà dé ọkàn ọmọ Jamaica èyí ló mú Panos Caribbean, ẹni tí ó ní ilé iṣẹ́ ìròyìn tí kì í ṣe ti ìjọba, láti fi orin kéde nípa ọ̀rọ̀ àyíká. Iléeṣẹ́ náà ti yege nínúu ìtànká àwọn ìkéde tí ó ṣe kókó nípasẹ̀ẹ iṣẹ́ Ohùn fún Àyípadà Ojú-ọjọ́. Kedere ni ohùn ń jáde láti inú ilé àpérò ìlú-mọ̀ńká United Nations Conference ní Paris (COP21) lọ́dún-un 2015. Níbẹ̀, ọ̀kọrin ọmọ Jamaica Aaron Silk darapọ̀ mọ́ àwọn olórin mìíràn pẹ̀lú eléré Belizean Adrian Martinez láti ṣe alágbàáwí ìdínkù fún ìgbóná àgbáyé sí ìwọ̀n-ọn ojúàmì 1.5. Ìfiránṣẹ́ olórin náà, tí ó ṣe àtìlẹ́yìn, ipòo ti ìdásílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Erékùṣù Kéékèèké Tí-ó-ń-gòkè, jẹ́ ohun àfiyèsí, tí ó ń ní ipa nínúu ìwé-ìpamọ́ ìkẹyìn-in ti COP21. Ọdún gorí ọdún, iṣẹ́ “1.5 túbọ̀ ń rinlẹ̀ sí i ní ìlà-oòrùn Caribbean, níbi tí àwọn ọ̀kọrin ti ṣe àlọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ akéwì St. Lucian Kendel Hippolyte’s pẹ̀lú orin-in ti wọn láti ṣe àrídájú wípé iṣẹ́ náà dé ibi tí ó yẹ kí ó dé. Wàhálà àyípadà ojú-ọjọ́ ní ọdún-un 2019 jẹ́ ohun tí ó nílò àbójútó kíákíá ju ti ìdúnrin lọ, àti ní Jamaica, àwọn ará ìgbèríko tí ó jẹ́ àgbẹ̀, àwọn apẹja ń gbọ́ ìpè itanijí yìí. Akọrin, ọmọ ilé ìwé àti àwọn aládùúgbò péjọ ní Kingston, Lionel Town, Ridge Red Bank àti White River fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rin nínúu oṣù Ẹrẹ́nà àti Igbe. Níbẹ̀, wọ́n fi ẹ̀kọ́ kún ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìtàkùrọ̀sọ àti kọ́ nípa ipa àyípadà ojú-ọjọ́. Ọ̀rọ̀ orin tí ó lágbára gbérí, ọgbọ́n ń tayọ àti ìrìnàjò ìṣíjú ojú ẹsẹ̀: Ìyá Ilẹ̀-ayé ń ké tantan Nínú igbó kìjikìji níbi tí àwọn igi ń wó sí Wo òkúta ìsàlẹ̀ òkun, wo ẹja bí ó ṣe kéré Fún wọn ní àsìkò, jẹ́ kí wọ́n dàgbà àti ga Àwọn akọrin láti Kingston, Clarendon àti Spanish Town ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lóríi ọ̀rọ̀ orin níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ìfiṣẹ́ránṣẹ́ Àyípadà Ojú-ọjọ́. Àwòrán-an Emma Lewis, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ. Pẹ̀lú ìfilọ́lẹ̀ẹ Panos fún àkòrí orin tuntun fún Caribbean fún Àyájọ́ Ilẹ̀-ayé, ẹgbẹ́ẹ Jamaica náà ti ṣe tán láti ṣe eré ní iléèwé àti ní àdúgbò, láì yọ Kàwé Jákèjádò Jamaica sílẹ̀ àti iṣẹ́ igi gbíngbìn. Àwọn orin báwọ̀nyí, tí a kọ sí orí ìlú reggae àtijọ́ tí a fi àlùjó kún, ṣe kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ mi ìgboro: Ìyá Ìṣẹ̀dá ń kérora fún ìwàláàyè Bí àwọn iléeṣẹ́ ṣe ń ṣiṣẹ́, ìyá ń ké. Ìgbà wo ni a óò kọ́ ẹ̀kọ́, tí a ó fi gbọ́n? Bí omi-dídì ilé ayé ṣe ń yọ́, òkun ń kún. Ta ni yóò jáwé olúborí nínú Ayẹyẹ ijó ìta-gbangba orílẹ̀-èdè Trinidad àti Tobago ọdún-un 2019?‬ Àwọn alárìíyá máa ń gba títì kan ní ọdọọdún fún Ijó ìta-gbangba Ijó ìta-gbangba Trinidad àti Tobago, tí wọn ń ṣe pẹ̀lú orin. Àwọn àṣàyàn orin tí wọ́n máa ń jó sí máa ń jẹ́ àkójọpọ̀ orin soca tí ó mi ìgboro títì nínú ọdún yẹn, àmọ́ Ìwọ́de Ojúnà orin náà tí máa ń jẹ́ jíjó jù lọ ní àwọn ibi kọ̀ọ̀kan ní ojú ọ̀nà ìyíde jẹ́ oyè tí ó mú ẹ̀bùn àti iyì ìgbélárugẹ àjogúnbá ohun àtijọ́. Fún àwọn òṣèré soca, kí ni kan ní í máa mú ni jáwé olúborí nínú Ìwọ́de Ojúnà, kò ju, dídáńgájíá ní oríi òpópónà. Ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn tàbí nnkan bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ pé ìdíje náà ní màgòmágó nínú pẹ̀lu ìlọ́wọ́sí àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ tí ó ni ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, afiorin-tí-a-ti-ká-sílẹ̀ dá àwọn ènìyàn lára dá àti àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́ orin kíkọ tí a mọ̀ sí “jàndùkú soca” kò ì yọ́ ìgbàgbọ́ wípé Ìwọ́de Ojúnà jẹ́ ohun àwọn ènìyàn. Ìràwọ̀ òṣèrée soca Machel Montano, ẹni tí ó ṣe ojúkòkòrò jáwé olúborí nínú Ìwọ́de Ojúnà ní ẹ̀rìnmẹ́sàn-án, ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “orin tí ó máa ń mú àwọn ènìyàn ní ìdùnnú àti tí máa ń mú àwọn ènìyàn jáde nínú ara wọn” akọrin wo ni kò ní fẹ́ gba irú oyè bẹ́ẹ̀? Àmọ́ kí ẹnikẹ́ni máà rò wípé iṣẹ́ ọpọlọ nìkan ni ìrìnàjò sí Ìwọ́de Ojúnà. Orin Ìwọ́de Ojúnà gbọdọ̀ ní àwọn èròjà tí ó ṣe kókó nínú kí ó tó lè kópa: Ó gbọdọ̀ ṣe é jó sí, síbẹ̀ ó ní láti dùn ún ní etí àwọn ènìyàn tí yóò “mú wọn gbàgbé ara” ní orí ìtàgé, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ orin tí yóò mú ayọ̀ jáde, èyí tí a mọ Ijó ìta-gbangba mọ́. Ègbè tí àwọn òǹwòran lè kọ tẹ̀lé orin, ní ìdásí àti ìdáhùn tí í ṣe àṣà calinda, tí calypso àti àdàlù ìgbàlódé, soca ti wáyé. Orin tí a gbé jáde ní ìgbà tí ó yẹ. Bí orín bá tètè jáde, tí kò sí dúró pẹ́ títí ní ìgboro, orin mìíràn tí ó ń bá a figagbága lè rọ́ ọ sí ẹ̀gbẹ́. Ní ọ̀nà mìíràn, bí orin tí ó dára gan-an bá pẹ́ jù kí ó tó jáde, àwọn ayírapadà lè máà ní àyè tí ó tó fún wọn láti mọ ọ̀rọ̀ orin náà ní ìgbáradì kí ọjọ́ Ijó ìta-gbangba ó tó dé. Ní ìgbà mìíràn ẹ̀wẹ̀wẹ̀, ìdíje Ìwọ́de Ojúnà máa ń ní orin àyànfẹ́ tí kò ní afigagbága rárá; kò sí rí bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn, ìfigagbága náà máa ń le dé ibi wípé ó máa ń ṣòro láti yan olúborí. Láì wípé ọ̀kan ju ọ̀kan lọ, àwọn wọ̀nyí ni orin tí a rò wípé yóò figagbága nínú Ijó ìta-gbangba Ìwọ́de Ojúnà Trinidad àti Tobago ọdún-un 2019… Pápáa Queen's Park Savannah, ibi tí ó ní ewéko bíi kàá-sí-nǹkan ní àárín gbùngbùn olú ìlú Trinidad, ni ibi tí ayẹyẹ Ijó ìta-gbangba àti ilé ìtàgé àjọ̀dún náà. Orin yìí dá lóríi agbègbè ayẹyẹ náà, àti ìrántí tí ó ti mú bá àwọn ayírapadà tí ó ti ń kópa láti ọdúnmọ́dún. Orin náà ń fi ọ̀wọ̀ wọ agbègbè náà: bí ẹni wípé Agbègbè Papa náà ni oòrùn ní àárín àgbá-ńlá Ijó ìta-gbangba àti ohun tí ó kù ń yí i ká. “Savannah Grass” jẹ́ ìpè sí ìrírí idán ayée àjọ̀dún yìí. Bẹ́ẹ̀ kọ́, àmọ́ bẹ́ẹ̀ náà ni, ìlù orin náà ba orin náà mú gẹ́gẹ́ bí àwọn olólùfẹ́ẹ Ijó ìta-gbangba tí ó máa ń gbádùn un Ijó ìta-gbangba ṣe máa ń fẹ́ ẹ. Orin náà dún dáadáa ní etí àti pé ó mú èèyàn gbàgbé ara rẹ̀, ní ọ̀nà tí ó ń mú kí àwọn ayírapadà ó máa gbé ẹsẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan bí wọ́n ṣe ń rìn/jó ní ojú ọ̀nà. Orin náà ṣe àmúlò àti àfikún àwòrán ìlànà Ijó ìta-gbangba bí a ti ṣe mọ̀ ọ́ ni ìgbà-dé-ìgbà, fídíò orin náà túbọ̀ ṣe àfihàn ìdàgbàsókè orin soca láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí í ṣe orin calypso. Bí kò bá ti ẹ̀ jáwé olúborí nínú ìdíje Ìwọ́de Ojúnà (bí ó ti lẹ̀ jé pé ó ní àyè tí ó pọ̀!), “Savannah Grass” yóò wà nínú àkópamọ́ orin soca gẹ́gẹ́ bí orin ìgbà-dé-ìgbà tí ó mú inú àwọn olólùfẹ́ẹ Ijó ìta-gbangba ní ibi gbogbo dùn. Ìwà tí ó dùn mọ́ni ti “playing mas'” àti jíjó sí orin ni wípé ní bákan, àwọn èèyàn máa ń ju ọwọ́ sí òkè, pẹ̀lú ohunkóhun tí wọ́n bá mú ní ọwọ́, títì kan ohun-mímu àti aṣọ inujú. Aṣọ inujú yìí ni wọ́n máa ń pè ní “àkísà”, èyí tí wọn máa fi ń nu àágùn bí wọ́n bá ń “fò sókè”. Ìlànà Ijó ìta-gbangba náà kò sọnù ní ara Super Blue, ẹni tí ó kọ “Get Something and Wave”, orin tí ó jáwé olúborí nínú Ìwọ́de Ojúnà ọdún-un 1991. Ó fọnrere àtinúdá náà ní ọdún tí ó tẹ̀lé oyè tí ó gbà pẹ̀lú “Bacchanal Time”, tí ó pa àṣẹ fún àwọn ayírapadà láti máa “fi ọwọ́” bí àwọn afọnfèrè brass ṣe ń kọrin “F-jam” tí gbogbo ènìyàn mọ̀ tàbí “tantana” tí ó ń dún ní abẹ́lẹ̀. Super Blue tí ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà fún irúfẹ́ orin kan tí ó dára fún ojú ọ̀nà: ó tún jáwé olúborí ní èèkàn sí i ní ọdún-un 1995 pẹ̀lú orin-in rẹ̀ ewì sí agbábọ́ọ̀lù kríkẹ́ẹ̀tì Brian Lara, tí ó pa á ní àṣẹ fún àwọn olùwòran láti “na pátákóo wọn sí òkè kí wọn ó ṣe àríyá”. “Ìjì Àkísà” ní àwọn ohun tí ó mú soca yàtọ̀ bíi irúfẹ́ lavway ìpè-àti-ìfèsì, pẹ̀lú àyè tí ó fẹ́ fún àwọn ènìyàn láti fi àkísà. Orin tí ó dára lórí ìtàgé fún àwọn ayírapadà láti tú ara sílẹ̀ àti “ṣeré tìkára wọn”, lè fi hàn kedere wípé kò kì í ń ṣe wàsá láti fi ọwọ́ rọ́ sí ẹ̀gbẹ́ nínú ìdíje Ìwọ́de Ojúnà ti ọdún nìí. Bí ó bá ní orin kan tí ń fi gbogbo ọ̀nà wá oyè Ìwọ́de Ojúnà ti ọdún yìí, ni orin yìí tí ó ní àyè láti jáwé olúborí: ìlù “soca tí ó tani jí”, ọ̀rọ̀ orin tí ó sọ nípa ìṣọ̀kan tí àjọ̀dún náà máa ń mú wá, àti ègbé ọlọ́pọlọ tí ó kó gbogbo ẹ̀yà tí ó ń kópa nínú Ijó ìta-gbangba náà pọ̀ tí ó ń bá òṣìṣẹ́ akọrin kiri, tàbí bí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Trinbago ṣe máa ń sọ, “famalay” rẹ (kí a máà ṣèṣì fi wé “ẹbí”) : Ṣé ẹ rí i , ẹ jẹ́ kí n sọ fún un yín ní ẹ̀rìnkan sí i, famalay ni famalay ń jẹ́ àti pé ó yàtọ̀ sí ẹbí tí ènìyàn ti wá Àwọn kan ní ẹ̀jẹ̀ ni àmọ́ wọn kò fẹ́ rí oòrùn Famalay kì í bẹ̀rù láyé láti tì ọ́ lẹ́yìn ní ìgbà gbogbo… Láì pa àṣẹ (yàtọ̀ sí abala kan tí Skinny kọ “fi ọwọ́ọ̀ rẹ hàn mí” àti “wá tẹ̀lé mi”, orin náà dàbí orin ológun. Ègbé soca tí ó dùn ní etí, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ orin dancehall díẹ̀díẹ̀, ti ń da orí àwọn ènìyàn rú ní ìtaja Ijó ìta-gbangba. Bí ó ti lẹ̀ jé pé ó ní àríyànjiyàn bóyá “Famalay” yóò kópa nínú Ìwọ́de Ojúnà tàbí kò ní í kópa, nítorí Skinny wá láti St. Vincent àti Grenadines, òfin sọ wípé bí “ọ̀pọ̀ àwọn akọrin tí ó ń lé orin” yẹ kí “ó jẹ́ ṣíṣe láti ọwọ́ọ ọmọ bíbíi Trinidad àti Tobago”, orin náà lè jẹ́ afigagbága – eléyìí sì jẹ́ ọ̀kan. Èyí kì í ṣe wípé orin mẹ́ta péré ni ó ń du oyè. Ó ku bí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta kí Ijó ìta-gbangba ó wáyé, àwọn orin wọn mìíràn tí ó ní akọrin obìrin Destra Garcia àti Patrice Roberts tí yóò mú ìdíje le fún àwọn ọkùnrin, àti bí àwọn akọrin soca ṣì ń gbé àwo orin tuntun jáde, ìfigagbága Ìwọ́de Ojúnà ọdún-un 2019 ṣì ń lọ lọ́wọ́. Akẹ́kọ̀ọ́bìrin kan tí ó jẹ́ ọmọ Tibet-Canada rí ìkọlu lórí ayélujára lẹ́yìn tí ó já ewé olú borí nínú ìdìbò àjọ-ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́. Ó rò pé, Beijing ló yẹ á bá wí. Leung Hoi Ching ni ó kọ́kọ́ kọ ìròyìn yìí tí a sì tẹ̀jáde ní èdèe Chinese lórí ilé ìgbéròyìn jáde ará ìlú Hong Kong, Stand News ní ọjọ́ karùn-ún-dínlógún, Oṣù Èrèlé, ọdún-un 2019. Zhao Yunlin ni ó tú ìmọ̀ọ rẹ̀ sí èdèe Gẹ̀ẹ́sì. Ní ọjọ́ kẹsàn-án Oṣù Èrélé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti Ifáfitì Toronto, ọgbà Scarborough dìbò yan ọmọ ọdún méjìlél'ógún kan tí ìlú abínibíi rẹ̀ jẹ́ Tibet, gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ìgbìmọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan tí a kéde èsì ìdìbò ọ̀hún, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ China tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ l'ókè òkun fi òǹtẹ̀ lu àpilẹ̀kọ ìfi-èhónú kan ní orí ẹ̀rọ-ayélujára, tí wọ́n sì ń t'ọ́ka àbùkù sí Lhamo pé ó ń l'ẹ̀díàpòpọ̀ pẹ̀lú àwọn àjọ tó ń jà fún òmìnira Tibet. Wọn rọ àwọn aláṣẹ ilé-ìwé ọ̀hún láti yọ ọ́ kúrò l'órí òye náà. Kòbákùngbé ìfèsì ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó ń gbé ní òkè òkun gbùngbùn òkè-odò China. Ìṣàmúlò ẹ̀rọ-alátagbàa ti Lhamo kún fún àwọn kòbákùngbé ìjábọ̀-ọ̀rọ̀ àti èyí tí ó ń pè fún ìwàa jàgídíjàgan, èyí tí kò ṣẹ̀yìn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òkè-òkun tí ó ń gbé gbùngbùn China. Bí àwọn ilé ìgbéròyìn sáfẹ́fẹ́ àgbàńlá-ayé gbogbo ṣe tán ìròyìn-in rẹ̀ ká, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà láti Hong Kong àti Taiwan gbìnnàyá láti gbéjàa Lhamo. Nínú ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwo orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú Stand News, Chemi Lhamo sọ pé òun nígbàgbọ́ pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ kò sẹ́yìn àwọn àjọ tí wọ́n ń bá Ìjọba China ṣe, ẹ̀sùn èyí tí àwọn òṣìṣẹ́ àgbà àjọ ọba China ti sẹ́ lé lórí. Kí a tó dìbò yìí, a ti yàn mí gẹ́gẹ́ bí igbá-kejì ààrẹ ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ fún oṣù mẹ́jọ gbáko, kò sì sí ohun kan tí ó ṣẹlẹ̀. Ní ìdakèjì, lẹ́yìn gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ẹ pàjáwìrì wọ̀nyìí, kò sí àní-àní pé àjọ kan ń gbìyànjú láti tìka bọ ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nwọ̀nyí ní bírípó. Ó pani lẹ́rìn-ín pé láti ìgbà yìí wá tí mo ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí igbá-kejì ààrẹ, bí mo ti ṣe ń ṣe ètò oríṣiríṣi tí n ò sì yé fi àwọn àṣàyàn ìhùwàsí mi l'éde, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó ti wádìí nípa àwọn ọ̀nà òṣèlú tí mo yàn ní ààyò. Ó tẹ̀ síwájú sí i pé ìwà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ akẹgbẹ́ òun láti gbùngbùn China tí ń yí padà. Ọ̀kàn nínú àwọn akẹgbẹ́ẹ rẹ̀ tí ó wá láti gbùngbùn China fi ìwàǹwara pè é níjà láti fi èrò rẹ s'óde lórí gbígba òmìnira Tibet. Ó tún gba àwọn ìpè kan, èyí tí ó ń kọ “orin pupa” (orin ọ̀tẹ̀ tí ó ń yín Ẹgbẹ́ Òṣèlú Chinese Communist Party). Àwọn orin wọ̀nyìí kò yé Lhamo, bó ṣe jẹ́ pé kò mọ èdèe Mandarin Ilẹ̀ China sọ. Bí àkànlù àtakò àti ìjàbọ̀ ṣe ń lọ lọ́wọ́ lórí ayélujára, àpapọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tí gbógun lọ sí ọ́fíìsì ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ láti lọ pè fún gbígbé èsì ìdìbò ọ̀hún yẹ̀wò. Ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ sì ti ti ìyàrá ìpàdée wọn pa fún ìgbà díẹ̀, nítorí ọ̀rọ̀ àbò. Chemi Lhamo ti jẹ́ ajàjàǹgbara akẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mélòó kan. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ tó ní áápọn ní ìlú àjọgbé àwọn Tibet tí ó wà ní Toronto àti pé ó ti kópa nínú ìjàfẹ́tọ̀ọ́ kan tí ó wáyé níta Akànkọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Confucius tí fáfitì ọ̀hún, ẹ̀ka ìbílẹ̀ àjọ ìsọdọ̀kan àṣà Ilẹ̀ China tí ìjọba China ń ṣe agbátẹrù fún lọ́nà tí ó fi ń mú kí China lágbára sí i ní ilẹ̀ òkèèrè. Ní ìgbà yìí wá, ó ti fi èrò ọkàn-an rẹ̀ hàn pẹ̀lú àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ìlú láti Hong Kong àti Taiwan lórí kókó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ̀, òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, ìdá-gbé nǹkan ṣe, ìjọba àwarawa àti àwọn kókó tó jọ mọ́ ọ ní ìpàdé ìta gbangba. Lhamo ò fi ìgbà kan bẹ̀rù láti sọ èrò ọkàn-an rẹ̀ jáde rí tàbí fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ Tibet- ó má ń wọ Chuba, aṣọ ìbílẹ̀ àwọn ọmọ Tibet, ní gbogbo ọjọ́ Ọjọ́rú. Títí di ìgbà ìdìbò, kò gbó-òórùn inúnibíni kán rí láti ọ̀dọ àwọn akẹgbẹ́ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ China. Èyí ni ó mú u fura pé ìkoni síta bíi ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ yìí kò sẹ́yìn àwọn aláṣẹ China. Láti èèyàn ogúnléndé aláìníbùgbé sí olórí ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ Kí ó tó rin ìrìnàjò lọ sí Canada ní ọmọ ọdún mọ́kànlá , Chemi Lhamo jẹ́ ẹni ogúnléndé tí kò rí ibùgbé kan gbé ní India. Àwọn òbíi rẹ̀ àgbà sá kúrò ní ilẹ̀ẹ wọn pẹ̀lú Dalai Lama ní ọdún-un 1959. Nínú hàhámọ́ ìnira tí wọ́n wà yìí, kò sí ibi tí òun àti mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lọ, tí wọ́n kà wọ́n kún. Nígbàkúùgbà tí wọ́n bá bí mí léèrè pé : ‘Ibo lo ti wá?’ Ara mi máa ń kótì láti dáhùn – Ìgbà mìíràn mà á pé India ni mo ti wá, ṣùgbọ́n wọn kò fún mi ní ìwé ìgbèlùú; nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀ mà á dáhùn pé Tibet ni mo ti wá, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá béèrè pé báwo ni Tibet ṣe rí, n ò mọ bí n ó ṣe dáhùn-un rẹ̀, ìdí ni pé China ò fún mi ní ìwé ìgbèlùú lọ sí Tibet. Ṣùgbọ́n ìrírí mi bí wọ́n ṣe ń rí mi bíi atọ̀húnrìnwá ti jẹ́ kí n ní ìmọ̀ nípa àṣà àwọn èèyàn mi: àṣà Tibet. Llamo sọ̀rọ̀ nípa ìrìnàjòo rẹ̀ lọ sí Canada, ọmọ kékeré akẹ́kọ̀ọ́ tuntun kan tí ó wá láti Tibet tí ó bá wá sí ìyàrá ìkẹ́ẹ̀kọ̀ọ́. Ara rẹ̀ yá gágá, inú rẹ̀ dùn láti ṣe alábàpàdé àwọn ọ̀rẹ́ tí ó wá láti ilẹ̀ẹ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló mọ̀ pé ó lé sọ èdè Tibet. Síbẹ̀síbẹ̀, nínú ìfún-ojúpọ̀, ó sọ fún un pé: “Tí a kò bá sọ èdè Tibet ńkọ́? Mo lè sọ Gẹ̀ẹ́sì.” N ò mọ̀ bóyá ojú ń tì í ni tàbí ẹ̀rí ọkàn ń jẹ́ ẹ. N ò mọ̀. Ṣùgbọ́n ìgbà náà ni mo tó mọ̀ pé àwọn ọ̀dọ́ Tibet kan ò fẹ́ sọ èdè wọn bí ẹni pé wọn kàn-án nípa fún wọn láti sọ èdè elédè. Ní ìgbà yẹn, Lhamo jẹ́ ọmọ ọdún 12. Ẹ̀míi rẹ̀ ò lé ‘lẹ̀ nípa ìdánimọ̀ọ rẹ̀, ó yìí ọkàn àwọn òbí rẹ̀ padà láti kó lọ sí àdúgbò tí àwọn ọmọ Tibet ń gbé. Láti ìgbà náà wá, ó kọ́ nípa èdè, àṣà àti ìṣẹ̀ṣe Buddha ti Tibet, ó sì di àjà-fún-ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn. Àwọn àdáyanrí ìwà Tibet bíi ìní elẹgbẹ́ ẹni lọ́kàn, ìbọ̀wọ̀ fún àgbà, àìmọ̀kan ní ìpilẹ̀ ìbàjẹ́, ti fún mi ní ìgboyà. Bí ìmọ̀ mi ṣe ń lé kún sí i nínú àṣà ìbílẹ̀ẹ mi, ní ìgboyà mi ṣe ń pọ̀ sí i. Agbára àti ìgboyà yìí, bí ó ṣe sọ, tí mú u láti lè sọ̀rọ̀ akin gẹ́gẹ́ bí atọ̀hùn-rìnwá àti ọmọ Tibet: Ó le láti jẹ́ atọ̀hùn-rìnwá, ṣùgbọ́n ìjàjàǹgbara yìí ní ó sọ mí di bí mo ṣe wà. Lónìí, mò ń sọ̀rọ̀ ní ohùn ìrara nípa àwọn ará Tibet ní kíkankíkan àti ìwúrí ọlọ́pẹ́ tí ìdánimọ̀ọ mi gẹ́gẹ́ bí ọmọ Tibet fún mi. Nígbà tí à ń dìbò ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́, mo máa ń tẹnu mọ ọn pé ó yẹ kí àwọn tí wọ́n ayàsọ́tọ̀ ní aṣojú nígbà ìdìbò. À ń fẹ́ aṣojú tí yóò rí i wípé à ń rí ẹtọ wa gbà lóòrèkóòrè. Ìjìyà yóò wá sópin Fún Lhamo, ayé tí ó pé pérépéré ni èyí tí kò sí ìdálọ́wọ́kọ́ tàbí ìyàsọ́tọ̀ Òmìnira Tibet àti ìdádúróo rẹ̀ kọ́ ni ohun tí ó hún jẹ wá lẹ́sẹ̀. Ìmísí ọjọ́ ọ̀la mi sí Tibet kan náà ni mo ní sì gbogbo àgbá-ńlá-ayé: Mo fẹ́ jẹ́ kí ẹ̀tọ́ tí àwọn ará Tibet ń jẹ gbádùn máà yàtọ̀ sí ti àwọn Canada, àwọn ni òmìnira láti lè sọ èrò ọkàn ẹni, òmìnira láti ní ìgbàgbọ́, òmìnira láti máà fi òṣèlú pá ẹniẹlẹ́ni lẹ́kún. N ò ṣe ojúṣàájú fún àwọn ará Tibet láti ní àwọn ẹ̀tọ́ wọn yìí nìkan, ó wù mí kí àwọn tí wọ́n wá láti Hong Kong àti Taiwan, ìwọ̀-oòrùn Turkey, àwọn ẹgb���ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ní ìlọ́po méjì 60 ẹni ogúnléndé tí ó wà ní kárí ayé àti fún gbogbo àwọn ènìyàn láti jàǹfààní ẹ̀tọ̀ wọ̀nyí. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn láti Hong Kong ní ìgbàgbọ́ pé China tí ń lo agbára tìkúùkú, wọ́n sì ń lo ètò ìlú láti ṣẹ́ àwọn ọ̀tá àti àwọn ẹ̀yà tí kò pọ̀ lẹ́yìn. Kódà ni Hong Kong, àyè láti sọ ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni jáde àti láti bá èèyàn ṣe pọ̀ ti jákulẹ̀. Àwọn ìpèníjà òṣèlú tí ó ń kojú wọn ní Hong Kong lẹ́yìn Àkójọpọ̀ Ẹgbẹ́ Alábùradà; 2014 Umbrella Movement kò ṣe àjòjì sí Chemi Lhamo, ṣùgbọ́n ó bá àwọn ará Hong Kong kẹ́dùn, ó pẹ̀tù sí wọn lọ́kàn pé kò kí wọ́n máà ṣe juwọ́ sílẹ̀: Mo kọ́ ẹ̀kọ́ kan nínú àṣà àwọn Tibet nípa àìwàfúnìgbàpípẹ́: gbogbo nǹkan ni òpin yóò dé bá. Mo ní ìgbàgbọ́ pé ìjìyà gbogbo ń bọ̀ wá dópin…Mo ní ìrètí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí mo máa wọ aṣọ Chuba mi lọ sí Tibet. Ìpolongo ìtakò Kérésìmesì ìlú China mú yíyan àjọyọ̀ le fún ọmọ-ìlú Kérésìmesì ń sún mọ́ dẹ̀dẹ̀ ṣùgbọ́n kàkà kí inú àwọn tí ó ń gbé ní orí-ilẹ̀ ìlú China ò dùn, ọ̀pọ́ ti fi ẹ̀hónú-u wọn hàn lórí ìpolongo tí ó tako ayẹyẹ Kérésìmesì tí ó kà á sí àjọ̀dún Òyìnbó. Ní ọdún 2017, ìgbìmọ̀ àgbà àti àjọ ìpínlẹ̀ lábẹ́ ẹgbẹ́ olóṣèlú Communist ìlú China kọ ìwé àṣẹ kan tí a pe àkọlée rẹ̀ ní “Ìmọ̀ràn lórí imúdiṣíṣẹ iṣẹ́ ìgbélárugẹ àti ìdàgbà àṣà ìbílẹ̀ China dé ibi gíga “. Wọ́n la àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìsọjí àṣà bíi Ọdún Òṣùpá Tuntun àti Àjọ̀dún Àtùpà sílẹ̀, láì pa ìyìókù tì, gẹ́gẹ́ bí ìpàgọ́ tí ó jẹ mọ́ ti àṣà tí ó lákaakì. Kí òfin yìí lè di àmúṣẹ, ìjọba China ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ètò ìpolongo kéékèèké mélòó kan fún ìkọ̀yìn sí àwọn ayẹyẹ tí kì í ṣe ti ìbílẹ̀ China. Ọdún nìín, ọjọ́ díẹ̀ sí Kérésìmesì, ìjọba ní àwọn ìlú ńlá bíi Langfang, ní agbègbèe Hebei, ti pa á ní àṣẹ fún ìsọ̀ gbogbo láti yọ ẹ̀ṣọ́ ọdún Kérésìmesì kúrò lójú títí àti fèrèsé. Ọ̀rọ̀ àlùfànṣá tí ó dá lórí ìtako àjọ̀dún Òyìnbó ti gba ẹ̀rọ-alátagbà ìlú China kan, èyí mú kí yíyan ayẹyẹ Kérésìmesì láàyò le koko fún àwọn tí ó rò wípé ní ìkọ̀kọ̀ ni ayọ̀ àwọn gbọdọ̀ wà. Ònlo Weibo Long Zhigao ya àwòrán ìròyìn orí WeChat ti rẹ̀ ní orí Weibo ní ìfihàn àríyànjiyàn. Kókó ìròyìn àkọ́kọ́ 1. Àjọ̀dún Òyìnbó ń bọ̀ lọ́nà dẹ̀dẹ̀. Kí a ṣe àjọyọ̀ àbí kí á máà ṣe é, ìbéèrè ni ìyẹn. 2. Ọmọ China ni mí n kò sì kí ń ṣe àjọyọ̀ Òyìnbó. 3. Sọ pé rárá fún ìṣàjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó nínú ọgbà ilé-ìwé. 4. Ẹgbẹ́ òṣèlú-ìpínlẹ̀ ti kọ ẹ̀yìn sí àjọ̀dún Òyìnbó. Àjọyọ̀ àjọ̀dún ti wa di ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Láfikún-un Kérésìmesì, àkàsílẹ̀ àwọn àjọ̀dún Òyìnbó kò yọ Àyájọ́ Ọjọ́ Olólùfẹ́, Àjíǹde àti Halowíìnì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sí ẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó ka àjọ̀dún sí “ìgbógunti àṣà” tàbí “ìrẹ̀sílẹ̀ ìlú”. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀kan tí ó ràn ká bí ìgbà tí iná bá ń jó pápá inú ọyẹ́ sọ wípé: Bí àwọn ènìyàn ìlú kan bá mú àjọyọ̀ àjọ̀dún ìlú mìíràn ní òkúnkúndùn ju bí ó ṣe yẹ, èyí fi hàn wípé orílẹ̀-èdè náà ń jẹ ìyà ìgbógunti àṣà. Bí ẹlẹ́gbẹ́ olóṣèlú kò bá mọ èyí, a jẹ́ wípé wọn kò ní ìkọbiarasí ìṣèlú wọ́n sì ti pàdánù ìlọsíwájúu wọn. Awuyewuye náà tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá Eight-Nation Alliance, ẹgbẹ́ ìṣọ̀kan tí a dá ní ìdáhùnsí Tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun Akànṣẹ́ ní China láàárín-in ọdún 1899 àti 1901 nígbàtí àwọn àgbẹ̀ rokoroko fi ẹ̀hónú hàn sí ìjọba amúnisìn, ètò ìṣèlú ní ìlànà Krìstẹ́nì àti àṣà. Síwájú sí i, ó ní wípé ọjọ́ ìbíi Mao Zedong, bàbá ìsàlẹ̀ Ìlú-tí-kò-fi-ọba-jẹ ti Èèyàn-an China, ni ó yẹ kí a kà sí Kérésìmesì ìlú China: Alága àkọ́kọ́ Ìlú-tí-kò-fi-ọba-jẹ ti China Mao Zedong ti yọ àwọn ènìyàn nínú ìṣòro. A gbọdọ̀ sọ ọjọ́ ìbíi rẹ̀ di Kérésìmesì China. Gbé ìgbésẹ̀ kí o kọ àjọ̀dún Òyìnbó. Àmọ́ àwọn ènìyàn kan lórí Weibo kò rí ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n kankan nínú àríyànjiyàn wọ̀nyí. Ẹnìkan sọ pé: Bí àwọn Òyìnbó bá ń ṣe àjọyọ̀ Ọdún Òṣùpá Tuntun, àwọn aráa China á gbéraga wọ́n á sì rí èyí gẹ́gẹ́ bí ìdàgbà ìsọjí àṣà ìbílẹ̀ China … Bí àwọn aráa China bá ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó, kí ni ìdí tí a fi kà wọ́n sí ìgbógunti àṣà? Àwọn ọ̀dọ́ máa ń ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó nítorí àríyá àti fún ayọ̀. Àwọn àjọ̀dún wọ̀nyí lè mú ìkóúnjẹjẹ gbòòrò, kí ni ó burú nínú ìyẹn? Àwọn kan gbèrò wọ́n fẹ́ gbé àjọyọ̀ Kérésìmesì fi ẹ̀gbẹ́ kan ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ìrẹ̀sílẹ̀ ìlú tí ó wáyé ní 160 ọdún sẹ́yìn. Fún kí ni? Ẹgbẹ́kíkó, ìkóraẹni-níjàánu Àgbàrá òdì ọ̀rọ̀ sí Kérésìmesì ti ṣàn gba orí ẹ̀rọ-alátagbà ó sì ti mú kí àwọn òǹlò kan ó kó ara wọn ní ìjánu. Ònlo Weibo kan fi ẹ̀hónú hàn: Kérésìmesì ń bọ̀ lọ́nà dẹ̀dẹ̀. Ní agbo ọ̀rẹ́ẹ wa, àgọ́ alòdìsí àjọ̀dún Òyìnbó àti alòdìsí alòdìsí àjọ̀dún Òyìnbó ń ṣe àríyànjiyàn. Kò kan ẹnikéni bóyá èèyàn féràn àjọyọ̀ tàbí kò fẹ́, kí ni ó dé tí àwọn ènìyàn ṣe fẹ́ràn láti máa fi túláàsì mú ẹlòmíràn gba èròńgbà ti wọn? Ojú kan tí gbogbo ènìyàn dúró sí ti kún. Fún àwa tí a wà láàárín, kí a ba mú un dọ́gba, a ní láti dúró sí ẹ̀gbẹ́ kejì. Awuyewuye ti kọjáa ti gbàgede orí ẹ̀rọ-alátagbà, ó kàn dé ilé-ìwé àti àjọ ìlú. Àwọn òǹlo Weibo kan ti pín ìkìlọ̀ ilé-ìwé ti a fún akẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀kan nínú ìkìlọ̀ náà (ọ̀tún) ń tọ́ka sí òfin “Ìmọ̀ràn” ó sì rọ olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ láti kọ àyájọ́ tí ó fi ara jọ ti Òyìnbó sílẹ̀. Bákan náà ni ìkìlọ̀ rọ akẹ́kọ̀ọ́ láti fọ́n iṣẹ́-ìjẹ́ òdì-ọ̀rọ̀ ìgbógunti àṣà Òyìnbó ká sí ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ lórí WeChat àti lórí àwọn irinṣẹ́ iṣẹ́-ìjẹ́ ẹ̀rọ-alátagbà mìíràn. Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún ìyá kan nígbàtí ọmọọ rẹ̀ kọ ẹ̀bùn Kérésìmesì. Ìyá kọ sórí Weibo: Ìyá: Ọmọ mi, ẹ̀bùn wo lo fẹ́ fún Kérésìmesì? Ọmọ: Èmi ò ní ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó kì í ṣe àjọ̀dún ìlúu China. Ó dáa, dájúdájú onígbọràn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn ará ìlú ni ọ́. Síbẹ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ṣe àròjinlẹ̀. Akẹ́kọ̀ọ́ kan ní ìbéèrè lórí òfin ilé-ìwé lórí Weibo: Ilé-ìwé ti gbé ẹsẹ̀ lé ìṣẹ̀ṣọ́ọ Kérésìmesì nínú ọgbà ó sì ti sọ pàṣìpàrọ̀ ẹ̀bùn di èèwọ̀ ní ìpolongo ìtako àjọ̀dún Òyìnbó. Ǹjẹ́ fún ìdàgbàsókè àṣà ilẹ̀ China ni gbogbo ọ̀nà yìí tàbí àmì ìpàdánù ìgbẹ́kẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ ẹni? Àwọn kan ti yan ìṣàjọyọ̀ àjọ̀dún náà ní ìkọ̀kọ̀. Òǹlo Weibo kan sọ: Ilé-iṣẹ́ ti sọ ayẹyẹ àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó di èèwọ̀. Ṣùgbọ́n akọ̀wé láti ẹ̀ka ètò-òṣìṣẹ́ ti fi òró Kérésìmesì (ẹ̀bùn Kérésìmesì tí ó wọ́pọ̀) fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ìkọ̀kọ̀. Ẹ jẹ́ kí a fẹ́ àlàáfíà. Òǹlo Weibo mìíràn fi èròńgbàa rẹ̀ hàn pẹ̀lú ohun tí ó fẹ́ fún Kérésìmesì: Ẹ kú ọdún Kérésìmesì! Mo nífẹ̀ẹ́-ẹ̀ rẹ olúwa! Bàba Kérésìmesì, jọ̀wọ́ fún mi ní ìbọsẹ̀ nílá gbàngbà pẹ̀lú òmìnira nínúu rẹ̀. Ìwọ́de afẹ́ àwọn abódiakọ-akọ́diabo àkọ́kọ́ lè tú èrò nípa wọn ní Pakístánì ká Jannat Ali Pẹ̀lú àwọn alágbèékalẹ̀ láti ilé-iṣẹ́ Sathi àti Track-T. Àwòrán láti ọwọ́ọ Syed Noman. A lò ó pẹ̀lú àṣẹ. Fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ẹ̀tọ́ àti imúdiṣíṣẹ ìbéèrè wọn lábẹ́ òfin, ìwọ́de Afẹ́ Abódiakọ-akọ́diabo wáyé ní Lahore, Pakistan, lọ́jọ́ 29 oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2018. Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn ìlúu nì, àwọn Abódiakọ-akọ́diabo kò bẹ̀rù láti jáde síta nínú ibi ìkòkọ̀ wọn àti fún ìjọba láti mú òfin Ààbò Ẹ̀tọ́ Abódiakọ-akọ́diabo Ènìyàn ọjọ́ 24, oṣù Èbìbì 2018. Ìwé òfin ìlú Pakistan sọ wípé “A kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ ìgbé ayé tàbí òmìnira du ẹnikẹ́ni ní ìbámu òfin,” tí ó wà lábẹ́ Àwọn Ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú. Síbẹ̀, Abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn ní ìtàn mìíràn láti sọ bí ó bá kan ti ẹ̀tọ́ àti ìgbé ayé; wọ́n ti jìyà oró, ìfipábánilòpọ̀, dáná sun wọ́n ní ààyè, bẹ́ wọn lórí àti yin ìbọn pa wọ́n, ìjọba kò fi torí gbogbo èyí ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú pé Ìjọba ti tari òfin Ààbò Ẹ̀tọ́ Abódiakọ-akọ́diabo Ènìyàn wọlé nínú oṣù Ẹrẹ́nà ọdún 2018. Jannat Ali, tí orúkọ ìnagijẹ r���̀ ń jẹ́ Lahore's Trans Diva, ni olùdásílẹ̀ Abódiakọ-akọ́diabo Track Transgender àti Olùdarí Ètò fún Ilé-iṣẹ́ Sathi tí ó ṣe àgbékalẹ̀ Ìwọ́de Afẹ́ náà. Àwọn Abódiakọ-akọ́diabo mìíràn àti àwọn tí kì í ṣe Abódiakọ-akọ́diabo àmọ́ tí ó jẹ́ alátìlẹ́yìn náà kó ipa nínú ìyíde náà àti àṣeyọríi rẹ̀. Ilé-iṣẹ́ ìpìlẹ̀ Sathi jẹ́ ilé-iṣẹ́ fún àlàáfíà àti ìmójútó ààbò ẹgbẹ́ abódiakọ-akọ́diabo ní Pakistan. Ènìyàn Abódiakọ-akọ́diabo tí ó tó bí 250 láti agbègbè jákèjádò ìlú Pakistan. Gbajúmọ̀ nínú wọn ni Kami Sid, Bebo láti Sindh, Nadra láti KPK, Anmol láti Agbègbè Sahiwal, Nayab láti Okara, Sunaina Khan (Oníjó ìbílẹ̀), Naghma àti Lucky (Akọrin Coke Studio), Laila Naz àti Neeli Rana. Ìpàdé oníròyìn ni a fi bẹ̀rẹ̀ ètò ní Ilé Ẹgbẹ́ Akọ̀ròyìn ní Lahore níbi tí wọ́n ti fi ẹ̀dùn ọkàn-an wọn hàn; lẹ́yìn náà ni wọ́n yide kiri dé Ilé Àṣà Al Hamra níbi tí wọ́n ti jó, kọrin lọ́nà, kí wọn ó tó fọ́nká lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán. Pẹ̀lú pé ìpàdé fún oníròyìn wáyé ní Ilé Ẹgbẹ́ Akọ̀ròyìn Lahore, Ìyíde Ìgbéraga náà ó jáde nínú ìròyìn. Bíótilẹ̀jépé àwọn alágbèékalẹ̀ fi ìwé pe aláṣẹ ìlú, bí i Punjab MNA Saadia Sohail láti Pakistan Tehreek e Insaf, àwọn aláṣẹ kò yọjú. Ìyíde ọ̀hún fa awuyewuye lórí ẹ̀rọ-alátagbà níbi tí àwọn ènìyàn gbé oríyìn fún ìyíde kiri náà nígbà tí àwọn ènìyàn kan fẹ́ mọ ìdí tí ilé iṣẹ́ oníròyìn kò ṣe rò nípa rẹ̀. Ni ọ̀rọ̀ọ rẹ̀ alágbèékáa Jannat Ali ní: Ìyíde náà tún tẹnu mọ́ ìlọsíwájú àti ìbáṣepọ̀ rere láàárín ẹgbẹ́ abódiakọ-akọ́diabo; bákan náà ni ó tẹnu mọ́ ìyàsọ́tọ̀ àti rògbòdìyàn. Nítorí wípé kò sí iṣẹ́ fún wọn, àwọn abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn kò ní ṣíṣe ju kí wọn ó ṣe òwò nọ̀bì láti rí oúnjẹ òòjọ́. Látàrí ìbálòpọ̀ tí kò ní ààbò, ọ̀pọ̀ l'ó ti kó àrùn kògbéwékògbègbó HIV àti AIDS. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ṣe kókó fún àjọ ọlọ́pàá àti oníṣègùn nítorí àwọn ni kì í mú ayé rọrùn fún Abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn tí ó bá ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ tàbí nílò ìrànlọ́wọ́ ètò ìlera. A ti fi ẹ̀tọ́ àwọn abódiakọ-akọ́diabo yí iyẹ̀pẹ̀. Láti ọdún 2015, abódiakọ-akọ́diabo tí ó tó 500 ni a ti rán lọ sí ọ̀run alakákeji ní Pakistan , Jannat Ali sì tún sọ wípé Abódiakọ-akọ́diabo 60 ni a dá ẹ̀mí wọn ní ẹ̀gbodò ní ọdún tí ó kọjá. Asad Zaidi túwíìtì nípa ojú tí àwọn ènìyàn Pakistan fi wo ẹgbẹ́ Abódiakọ-akọ́diabo: Nínú ọ̀rọ̀ọ rẹ̀ ní TEDxLahore ní ọdún 2017, Jannat Ali ṣe àlàyé ìrìnàjòo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí abódiakọ-akọ́diabo ní Pakistan lẹ́yìn ìgbà tí ó fi irú ènìyàn tí òun ń jẹ́ han ẹbí àti àwọn ènìyàn. Òfin Ẹ̀tọ́ Ààbò Abódiakọ-akọ́diabo Ènìyàn ọdún 2018 tí a bu ọwọ́ lù nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin fi àṣẹ fún ọmọ ẹgbẹ́ náà láti gba ìwé àṣẹ ọkọ̀ wíwà, ìwé ìrìnnà, ní ẹ̀tọ́ láti pààrọ ìṣẹ̀dá ẹni nínú àkọsílẹ̀ ìlú àti Àjọ Ìforúkọsílẹ̀ (NADRA), ìfòpinsí ìjìyà, àyè láti kàwé, iṣẹ́ nínú káràkátà àti ètò ìlera láì sí ìyàsọ́tọ̀. Òfin náà ní ìjọba yóò pèsè àyè ilé ààbò fún Abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn, ètò ìlera àti ohun èlò ẹ̀kọ́ àti ilanilọ́yẹ. Wọ́n máa lè jẹ ogún àti ẹ̀tọ́ láti di ìbò. Pakistan ti ń sún kẹ́rẹ́ ní ti ìgbé ayé Abódiakọ-akọ́diabo. Díẹ̀ lára àwọn abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn du ipò ìjọba nínú Ìbò ọdún 2018 fún ìgbà àkọ́kọ́. Ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán ìbílẹ̀ kan gba Abódiakọ-akọ́diabo àkọ́kọ́ sí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí atọ́kùn; Coke Studio, ètò orin, àwọn Abódiakọ-akọ́diabo méjì ni ó ti kópa ní orí ètò náà. slowly starting to make strides when it comes to transgender visibility. Bí nǹkan ṣe ń ṣe ẹnu ire fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Abódiakọ-akọ́diabo a sì ń gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, ìrìnàjò náà kò yàrá. Síbẹ̀, ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn ni ó ní ìgbàgbọ́ wípé àyípadà ọ̀tún ń bọ̀ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti gbé ìgbé ayé ìfọkànbalẹ̀ nígbà tí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn gbogbo ní ìlú á wà ní ọ̀gbọọgba ní ojú àwọn ènìyàn àti ní abẹ́ òfin. Àdàwólulẹ̀ ilé ayé-àtijọ́ ọlọ́dún-un 150 fi àìkáràmáìsìkí ìjọba sí àwọn ibi àjogúnbáa Bangladesh hàn Ní Dhaka, ilé àjogúnbá ọlọ́gọ́rùn-ún ọdún kan di àdàwólulẹ̀ pátá ní alẹ́ ọjọ́ Ìtunu Àwẹ̀ 5, oṣù Òkúdù 2019. Ní nǹkan bíi ọdún-un 1870 ni a kọ́ ilé náà tí ó fẹ́ẹ́ dà bíi ọkọ̀ ojú-omi, tí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ń pè ní “Jahaj Bari”, òun sì ni ilé àyágbé àkọ́kọ́ ni olú-ìlúu Bangladesh. Àdàwólulẹ̀ tí a da ilé yìí ti mú kí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn ó sọ ẹ̀dùn ọkàn-an wọn síta lórí àìbìkítà fún àwọn ilé tí ó jẹ́ ohun ìṣúra Dhaka. Ìròyìn fi yé wípé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó wà lórí ipò ìyẹn Awami League gbé ẹ̀rọ tatapùpù wá sí ibẹ̀, wọ́n sì da ilé náà wó. Àwọn tí ó wá ṣiṣẹ́ náà sọ wípé olóríi àwọn, ọmọ ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀ (Dhaka-7) Haji Md. Salim, ti ra ilẹ̀ náà láti fi kọ́ ilé alájà tó pọ̀ sí ibùdó náà. Bákan náà àwọn alátìlẹ́yìn AL sọ wípé ilé àtijọ́ náà kò sí lóríi àwọn ibi àjogúnbá tí ó wà nínú àkọsílẹ̀. Ní ọjọ́ 13, oṣù Ògún ọdún-un 2018, Ilé-ẹjọ́ Gíga Dhaka pàṣẹ fún àjọ ìjọba tí ó ń rí sí ètò ìdàgbàsókè ìlú ní ìlànà tìgbàlódé ní Dhaka láti máà wó tàbí tún àwọn ilé àjogúnbá tí ó wà ní olú-ìlú náà tó bíi 2,200 kọ́. Jahaj Bari wà nínú àwọn ilé àkọ́pọ̀ Waqf (mortmain) tí kò ṣe é tà. Gẹ́gẹ́ bí alákòóso Bangladesh Waqf Administratioń ṣe sọ, gbígba àṣẹ pọn dandan láti gbé iṣẹ́ sílẹ̀, tà tàbí ṣe àtúnṣe sí ohunkóhun tí ó bá jẹ́ ti Waqf. Èyí kò rí bí ajàfẹ́tọ̀ọ́ AL náà ti ṣe wí, kò sí ohun tó jọ ọ́, kò sí àṣẹ tí ó ní kí wọ́n tà tàbí wó ilé tí à ń sọ̀rọ̀ọ rẹ̀ yìí. Nínú oṣùu Ẹrẹ́nà ọdún-un 2019, a gbé ìgbésẹ̀ kan láti da ilé náà wó lulẹ̀. Urban Study Group, ẹgbẹ́ aṣiṣẹ́ ọ̀fẹ́-tí-kò-ní-èrè tí ó máa ń fi ààbò fún àwọn ohun àjogúnbá Dhaka Àtijọ́ fi ìwé ẹ̀dùn ìdáwọ́dúróo àdàwólulẹ̀ náà ránṣẹ́ sí àwọn tí ọ̀rán kàn, tí ó sì mẹ́nu ba àṣẹ Ilé-ẹjọ́ Gíga. Síbẹ̀, bí ìwé ìròyìn ṣe jábọ̀, díẹ̀ lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ń yọ̀ fún àdàwólulẹ̀ ilé náà. Wọ́n ò mọ̀ pé ilé náà ti di ẹgẹrẹmìtì, ó sì lè wò lulẹ̀ kí ó wó lù wọ́ntí í ṣe àpẹẹrẹ àìmọ̀kanmọ̀kàn àwọn ènìyàn sí ìpamọ́ ohun àjogúnbá àti àtìlẹ́yìn fún àtúnṣe sí ilé àtijọ́ tí ó wà ní Bangladesh. Àjogúnbá Ìṣẹ̀lẹ̀ Àtẹ̀yìnwá ọ̀rọ̀ tí ò jẹ́ mọ́ nǹkan Ọ̀pọ̀ ènìyàn l'ó fi ẹ̀dùn ọkàn-an wọn hàn nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa àmúdipẹ̀tẹ́lẹ̀ ilé náà. Shuvra Kar kọ sí oríi Facebook: Àjogúnbá , ìtàn-ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá, àṣá jẹ́ ọ̀rọ̀ tí kò já mọ́ nǹkan ní orílẹ̀-èdè yìí! Òǹkọ̀wé Tania Kamrun Nahar tan ìmọ́lẹ̀ sí ìdí tí kò fi yẹ kí ilé yìí di àdàwólulẹ̀: Ilé alájà-mẹ́ta náà “Jahaj Bari” ní àwọn iṣẹ́ ọnà tí ó yàrà ọ̀tọ̀ lára ní ara irin àgbọ́wọ́lé gun àkàsọ̀. Iṣẹ́ ọnà aláràbarà ti orí òrùlé ibi ìbojúwòta gígùn. Ọ̀kanòjọ̀kan ọnà ni ó wà ní ara ilé náà àwọn àràbarà ọnà abẹ́ àjà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn òpó ní àwòṣe ọnà ilée ionic àti Corinthian. Ọnà ara ilé náà kọjá àfẹnusọ tí a kò le è rí lára àwọn ilé mìíràn ní àwọn agbègbè àtijọ́ọ Dhaka. Fún ìdí èyí, kò yẹ kí ilé náà di àdàwólulẹ̀. Ọdún-un 1610 ni Dhaka di olú-ìlúu Bengal, ìyẹn ogójì ọdún sẹ́yìn. Ní sáàa Mughal àti ìjọba amúnisìn British, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé tí a kọ́ ni ó ní ìtàn-ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá àti àjogúnbá ìlú náà kan tí ó rọ̀ mọ́ ọn. Àmọ́ púpọ̀ nínú àwọn ilé wọ̀nyí ni ó ti wó láti ọjọ́ pípẹ́. Àwọn tí ó ṣì ń dúró ti di ẹgẹrẹmìtì, èyí á mú kí àwọn kan ó máa lọ (ṣe ayédèrú ìwé láti) gbẹ́sẹ̀ lé ilé wọ̀nyí. Àpẹẹrẹ kan ni Bara Katra, àrágbáramúramù ilé tí ó ní ìtàn-ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tí Mir Abul Qasim, Diwan (alága ètò ìṣúná) ti ó jẹ́ ọmọba Shah Shuja Mughul kọ́ ní nǹkan bíi 1644 àti 1646. Ó jẹ́ nǹkan ìbànújẹ́ wípé ilé náà ti ṣe tán, ó lè wó nígbàkigbà látorí àìṣàtúnṣe, àìkáràmáìsìkí ohun àjogúnbá, àti ìbàjẹ́ tí àwọn tí ó gbé ilé láì gba àṣẹ ń fà. Muntasir Mamun ti kọ àìmọye ìwé lóríi ìtàn-ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá àti àjogúnbá ìlúu Dhaka. Ó kọ sínú ìwé ìròyìn ìbílẹ̀ẹ Bhorer Kagoj: Mo ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn aláṣẹ fún ogójì ọdún tí ó kọjá láti gba àwọn ilé àjogúnbá bíi Bara Katra àti Choto Katra sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó fẹ́ pa ìtàn àtẹ̀yìnwá rẹ́. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn. Kí ni ká sọ? Nígbà tí ẹ̀ka tí ó ń ṣe àkópamọ́ sítám̀pù ti wo ògiri àtijọ́ àmọ̀káyée Lalbagh Fort láti fi ṣe àyè ìgbọ́kọ̀sí, báwo ni a ó ṣe dojú ìjà kọ ìwà òmùgọ̀? Ilé oníròyìn orí-ayélujára kan ti ṣe àtẹ̀jáde àbájáde ìwádìí tí ó jinlẹ̀ nípa àìkáràmáìsìkí ìjọba lóríi àwọn ilé àjogúnbá àti àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ tí ó ń gbìyànjú láti da àwọn ilé tí ó kù wó: Ilé tí ó wà ní ipò.14 ní orí ìwé àkọsílẹ̀ àjogúnbá ti di wíwó. Apá kan lára àwọn ilé àwòṣífìlà tí ó wà ní Sutrapur kò ṣe é rí mọ́n. Iṣẹ́ àtúnṣe sí àwọn àjogúnbá ìgbàa Mughal ní mọ́ṣálááṣí Bangshal Mukim Bazar Jam-e àti mọ́ṣálááṣí Siddique Bazar Jam-e ti di ohun ìgbàgbé nítorí ojú àpá ò le è jọ ojú ara, ó ti yàtọ̀. [..] Àmọ́ ṣá, ó ní àṣẹ ìjọba tí ó fi ààbò bo àwọn ilé àjogúnbá, àwọn agbèfúnjọba ti agbègbèe Rajdhani Unnayan Kartripakkha àti Àjọ Ìlúu Dhaka kò ṣe ohun tí ó yẹ kí wọn ó ṣe. Àìṣojúṣe wọn ni ó fà á tí àwọn olóṣèlú olójúkòkòrò ṣe ń gba àwọn ilé àtijọ́ tí wọ́n sì ń dà wọ́n wó lulẹ̀. Ẹgbẹ́ Urban Study ti ṣe àgbékalẹ̀ ìwọ́de àti àkójọ àwọn ènìyàn tí yóò fi ẹ̀hónú àdàwólulẹ̀ wọ̀nyí hàn. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n gbèrò láti ṣe ìkéde nípa ìdààbò bo àwọn ilé àjogúnbá tí ọ̀rán kàn. Àwòrán ìsàlẹ̀ yìí ni àwọn ilé àjogúnbáa Bangladeshi tí àdàwólulẹ̀ ń bá: Àwọn ọmọ Bangladeshi lo ẹ̀rọ-alátagbà fi gbógun ti àjàkálẹ̀ àìsàn ibà-ẹ̀fọn Ní àárín ọdún, mélòó kan tí ó kọjá, pàápàá ní àsìkò ìjì ọdọọdún monsoon, iye àwọn tí àìsàn-an ibàa ẹ̀fọn ti kọlù ní Bangladeshì ti lékún síi. Ní ọdún yìí, àwọn tí àìsàn-an ibàá kọlù tó bíi 7,179, àwọn - 2800 ní sáà kínní osùu Agẹmọ nìkan. Bí ètò ìjọba ò ṣe dántọ́ tó láti borí àjàkálẹ̀ àìsàn ibà tí ó gbòde yìí, àwọn ènìyàn ń gbẹ́kẹ̀le ẹ̀rọ-alátagbà láti fi sọ ẹ̀dùn-un ọkàn-an wọn, pín àlàyé nípa ìtànkálẹ̀ kòkòrò náà, àti ṣe ìkéde nípa bí àwọn ènìyán ṣe le dá ààbò bo ara wọn. Ibà-ẹ̀fọn ní Bangladesh: ó tó bíi ẹni 2800 tí àìsàn-an nì tẹ̀ wò nínúu àwọn ọjọ́ mẹ́rìndínlógún àkọ́kọ́ osùu Agẹmọ Àkọsílẹ̀ Àìsàn Pọ̀ Sí i Ní Osù Agẹmọ Ilé ìwòsàn gba àwọn aláìsàn ibà ẹ̀fọn 403 tí ó pọ̀ jù lọ ní ọjọ́ 22 osù Agẹmọ. Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ kan ṣe rò, ipa ìyípadà ojú-ọjọ́, òjò àìdágbá kan, ojú-ọjọ́ tó ń ṣe ségesège, àti àìṣèmọ́tótó ni ọ̀dádá tí ó ń dá àtànkálẹ̀ ibà sílẹ̀. Àwọn mìíràn sọ wípé ibà ẹ̀fọn ti ọdún nìí ń ṣekú paon ju ti ẹ̀yìn wá lọ. Ní ti òǹlò Twitter “Ibà-ẹ̀fọn àti àmìi rẹ̀ ní ọdún yìí ti yàtọ̀ nítorí ìdí èyí ni o fi ní láti tọ oníṣègùn rẹ̀ lọ ní kété tí o bá ti ní ibà náà” – gẹ́gẹ́ bí ògbólògbó onímọ̀ ìlera ti Ilé-ìwòsàn Bangabandhu ti sọ. Àwọn ẹ̀yà ara àwọn aláìsàn tí amodi tẹ̀ ti ń daṣẹ́ sílẹ̀ – a kò gbọ́ èyí rí. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ìwé ìròyìn Bangla Tribune, Dókítà Gulzar sọ wípé kò sí bí a ṣe lè wo ibà ẹ̀fọn yìí nígbà àkọ́kọ́ tó, kí ó máà tún ṣeni lẹ́ẹ̀ẹkejì. Ibà-ẹ̀fọn ti ọdún yìí jẹ́ tuntun, ó sì yára pa ènìyàn. Ó sì ń fa àmì ìfòyà. Ohun tí ó lè fà á lè pọ̀ – ọ̀pọ̀ ni ó kó àìsàn ní ọdún tí ó kọjá, tí wọn kò fura. Bí ó bá tún tẹ̀ wọ́n ní ẹ̀rìn kejì, sààárè ń sún mọ́ nìyẹn. Ìròyìn nípa àjàkálẹ̀ àìsàn yìí ń gba gbogbo orí ẹrọ-alátagbà kan tí ó sì ń mú àìbalẹ̀ara àti ọkàn bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òǹlo ẹ̀rọ-alátagbà. Shofiq Ahmed pín Túwíìtì kan nípa ìròyìn àìsàn tuntun: Alákòóso Olùgbé Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé náà papàá ti ní àìsàn ibà-ẹ̀fọn. . Òǹlo Twitter Shorbo Bosonto wípé: Àwọn dókítà méjì kan náà kú látàrí ibà-ẹ̀fọn, èyí sì ti ń mú kí àwọn ènìyàn ó máa bẹ̀rù. Ilé-ẹjọ́ Gíga Dhaka ti fi àṣẹ pe Ọ̀gá Àgbà Ètò Ìlera ti ìjọba. Àwọn tí ó ń kú nh pọ̀ ọ́ sí i. Ǹjẹ́ ìjọbá ń ṣe tó? Ojú-ìwé Facebook ti BBC Bangla rọ àwọn òǹkàwée rẹ̀ láti jábọ̀ àwọn ìgbésẹ̀ akin tí àwọn òníṣẹ́ ìlú Dhaka ń gbé láti gbógun ti ẹ̀fọn. Òǹlò Mohammad Mynuddin jábọ̀ ìfàsẹ́yìn láti ọwọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láti kápá àjàkálẹ̀ náà: A ò tíì rí nǹkan. Òṣìṣẹ́ Àjọ Ìlú kan ti sọ wípé yóò tó ọ̀sẹ̀ mélòó kan kí egbògi ìdáààbòbò tí yó sì dín ẹ̀fọn kù. Ó yà mí lẹ́nu Àwọn kan lérò wípé ìjọba ò mú kiní ibà-ẹ̀fọn ọ̀hún ní kanpá, àwọn ọmọìlú ń lo ẹ̀rọ-alátagbà mú kí àwọn ènìyàn ó mọ̀ nípa kòkòrò náà. Health Barta gbé fídíò kan sí oríi YouTube tí ó ń ṣe àlàyé lẹ́kùnúnrẹ́rẹ́ ohun tí ó pọn dandan láti ṣe bí èèyán bá ní ibà-ẹ̀fọn: Ọ̀gọ̀rọ̀ l’ó ń d'orí kọ ẹ̀rọ-alátagbà lọ láti gba ẹ̀jẹ̀ fún àwọn aláìsàn. Òǹlo Sajid Islam Khan túwíìtì pé òún nílò ẹ̀jẹ̀ fún àbúrò òun tí ibà-ẹ̀fọn ń bá fínra. Hannan Gazi náà se àgbéjáde tirẹ̀: Chittagong ṣe àgbéjáde túwíìtì: Àmì ibà-ẹ̀fọn àti àtiṣe.. Ní àárín-in àjàkálẹ̀ náà, Alákòóso-ìlú Àríwá Dhaka ti fagilé ìsinmi ránpẹ́ àwọn ikọ̀ tí ó ń rí sí pàntí kíkó àti ìgbégidínà àpọ̀si ẹ̀fọn. Síbẹ̀síbẹ̀, fún ìdáààbò àwọn ènìyàn, ṣíṣe ṣì kú. Ìṣọdẹ-àjẹ́ ṣì ń gba ẹ̀mí àwọn ènìyàn ní ìgbèríko India Ìletò kan ní ẹ̀báa Jamshedpur ní Jharkhand. Àwòrán láti ọwọ́ọ Anumeha Verma Ní ọjọ́ 20 oṣù Agẹmọ, àgbájọ àwọn ènìyànkéènìà gba ẹ̀mí àwọn àgbàlagbà mẹ́rin kan láì dá wọn lẹ́jọ́ ní agbègbèe Gumla ní Jharkhand, India lẹ́yìn tí a fi ẹ̀sùn-un àjẹ́ kàn wọ́n. Gẹ̀gẹ̀ bí ìjábọ̀ ìròyìn, àwọn àgbàlagbà wọ̀nyí ṣe ikú pa ọkùnrin kan, ni ìgbìmọ̀ abúlée Panchayat ṣe dá wọn lẹ́bi. Wọ́n wọ́ àwọn àgbàlagbà mẹ́rin wọ̀nyí jáde síta ilée wọn, àwọn ọkùnrin tí ó bòjú sì fi igi lù wọ́n títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lára wọn. Mẹ́jọ nínú àwọn ènìyànkéènìà wọ̀nyí ti wà ní akóló ọlọ́pàá. Gẹ̀gẹ̀ bí àkọsílẹ̀ ọlọ́pàá tí Times of India tẹ̀jáde, ìṣọdẹ-àjẹ́ ní Jharkhand ti rán àwọn ènìyàn 123 sọ́run àpàpàǹdodo ní àárín-in oṣù Èbìbí ọdún-un 2016 sí oṣù Èbìbí ọdún-un 2019. Jákèjádò, ènìyàn 134 di ẹni ẹbọra-ń-bá-jẹun látàrí èsùn-un lílo “ògùngùn” ní ọdún-un 2016, ìyẹn gẹ̀gẹ̀ bí Àjọ Aṣàkọsílẹ̀ Ẹ̀ṣẹ̀ Orílẹ̀-èdè náà ṣe kọ́ ọ sílẹ̀. Àrùn T’ó Ń Peléke Sí i “Ìṣọdẹ-àjẹ́ kò jẹ́ tuntun ní Jharkhand,” Prem Chand, Olúdásílẹ̀ àti Alága Free Legal Aid Committee ní Jharkhand, sọ nínúu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò orí ẹ̀ro-ìbánisọ̀rọ̀ kan. FLAC ti ń ṣe àtọ́nàa ìṣòfin tí ó tako ìṣọdẹ-àjẹ́ ní Jharkhand. Iléeṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní agbègbè yìí ní ọdún-un 1991 nígbà tí àwọn aládùúgbò fi ẹ̀sùn kan obìnrin kan pé ó lọ́wọ́ nínú ikú ọmọdékùnrin kan. Àgbájọ àwọn ènìyànkéènìà kan dìgbò lù ú, wọ́n sì pa ọkọ àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. Òún fi ara pa. Nígbàtí Prem Chand àti àwọn ẹlẹgbẹ́ẹ rẹ̀ ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wọ̀nyí nínúu túbú, wọ́n bá ìpèníjà: Wọ́n sọ fún wọn wípé àwọn dúró lé oríi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn. Wọ́n sì tún gbàgbọ́ wípé bí ẹ̀jẹ̀ẹ ẹni tí a pè ní àjẹ́ bá kan ilẹ̀ ọ̀gẹ́rẹ́, yóò pàdánù agbára ẹlẹyẹ rẹ̀. Prem Chand sọ wípé ó kan apá kan nínú àwọn ọmọ ìlú: Nígbàgbogbo, àwọn obìnrin tí kò lárá tí ó tálákà ní í máa ń fi ara kááṣá. Àwọn tí ó f’ara kááṣá wọ̀nyìí ni àwọn Adivasis, Harijans àti Dalits. Ìfojú iyì àwọn obìnrin àti ìtasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin ẹ̀tọ́ sí ayé iyì fún gbogbo ọmọ ènìyàn. Òtítọ́ Àwùjọ àti Ìṣèlú Àwọn ajìjàngbara sọ wípé ìgbàgbọ́-asán tí ó rinlẹ̀ ní ìgbèríko ni ó ń fa ìwà pálapalà náà. Àìgbẹ̀kọ́, ètò ìlera tí ò pójú òṣùwọ̀n àti kòlàkòṣagbe tí ó ń gb’àgbègbè tí ìwà pálapalà wọ̀nyí ti gbalẹ̀ bí i ìtàkùn ni ó fi wọ́pọ̀. Ọ̀ràn wọ̀nyí ti fi hàn wípé àhesọ ni ó máa fi ń bẹ̀rẹ̀. Pẹ̀lú òfin àwọn ìpínlẹ̀ India tí ó ka ìṣọdẹ-àjẹ́ sí ohun tí ó lòdì sófin, àwọn akópa ọ̀ràn wọ̀nyí rí i gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìdáààbò-ara-ẹni. Bákan náà ni wọ́n ń wí àwáwí fún gbígba ohun ìní àwọn obìnrin, fi agbára gbẹ̀san tàbí fi ipá bá obìnrin lò pọ̀. Gẹ́gẹ́ bí Prem Chand ṣe ti sọ: Àtètèròtẹ́lẹ̀ ni wípé ní kété tí o bá ti pe obìnrin ní àjẹ́, o lè tẹríi rẹ̀ ba fún ìlòkulò. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣe kókó láti mọ̀ wípé wọn máa ń lo ìwà pálapàla yìí fi gba tara àwọn obìnrin, kò sì kìí ṣe ìdí tí ó ń fà á pàtó. Ní ti ẹ̀fẹ̀, láì wí tó, panchayat náà sábà máa ń lọ́wọ́ sí ìpènìyàn ní àjẹ́ pàápàá bí kò bá pàṣẹ ìjìyà t'ó tọ́. Ní àfikùn sí panchayat tí ìbó yàn, àwọn kan ńbẹ tí wọ́n pe ara wọn ní panchayat ipò-ìsàlẹ̀ láì ní àṣẹ kankan tí ó fún wọn lágbara níbikíbi ní orílẹ̀-èdè. Àwọn ẹgbẹ́ yìí máa ń dájọ́ àti fi ìyà jẹ ènìyàn tí kò sì sí ẹni tí ó ká wọn lápá kò. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní agbègbèe Ajmer ní Rajasthan lọ́dún-un 2017 jábọ̀ ìlọ́wọ́sí panchayat ipò-ìsàlẹ̀ tí ó ṣ’okùnfa ikú obìnrin ogójì ọdún kan. Gẹ́gẹ́ bí òfin, ilé ẹjọ́ lé gbé ìgbésẹ̀ tí ó tako irúu ìdájọ́ báwọ̀nyí yálà láti ọ̀dọ̀ àwọn panchayat tí ìbó yàn àti panchayat ipò-ìsàlẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn tí ó fara kááṣá ò tilẹ̀ ní àǹfààní sí ilé-ẹjọ́ òfin kí àgbájọ-àwọn-ènìyànkéènìà ó tó kojúu wọn. Àwọn Ẹni-tó-fara-kááṣá àti Ẹni-tórí-kó-yọ Àwọn ènìyàn ń f’ẹ̀sùn kan àwọn ẹlẹyẹ fún iṣẹ́-ibi ọwọ́ọ wọn: ikú ènìyàn tàbí ẹranko, ọ̀dá òjò, àìso jìngbìnnì irúgbìn, àti bẹ́èbẹ́è lọ. Ìkọlù tí ó kọ lu àwọn obìnrin wọ̀nyí (àti àwọn ọkùnrin kan) rorò bí ẹranko ẹhànnà. Nígbà mìíràn, àwọn èsùn náà àti ìjìyà ẹṣé máa wá láti ọ̀dọ̀ mọ̀lébíi wọn. Àwọn kan ń gbé tí wọ́n sì ń sọ ìtàn-an wọn tí wọ́n sì ń jà fún ẹ̀tọ́ọ wọn. Chutni Mahato ti Saraikela ní Jharkhand jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Àwọn ènìyàn láti agbègbè náà máa ń pè é ní ‘tigress’. Wọ́n fi ẹ̀sùn-un àjẹ́ kàn-án ní ọdún-un 1995. Láti ìgbà náà, ó ti yírapadà di ajìjàǹgbara olùtako ìfìyàjẹ àwọn obìnrin pẹ̀lú àtìléyìn Ilé-iṣẹ́-tí-kìí-ṣe-tìjọba. Chutni sọ bí àìsí àtìlẹ́yìn tó késejárí ṣe mú u nira láti jà tako ìwà pálapàla yìí. “Ìbájẹ́pé àtìlẹ́yìn tó tó wá láti ọwọ́ àwọn oníṣẹọba àti ìjọba fún iṣẹ́ tí à ń ṣe níbí. Síbẹ̀síbẹ̀, mo ti jìyà nítorí ìwà pálapàla yìí. Bí ènìyàn bá tọ̀ mí wá fún ìrànlọ́wọ́, mo máa dúró tì wọ́n gbágbágbá,” ó sọ nínúu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò orí ẹ̀ro-ìbánisọ̀rọ̀ kan. Dídá Ohùn Gbogboògbò Sí i Àwọn ẹni-tórí-kó-yọ àti ajàfẹ́tọ̀ọ́-ènìyàn rò wípé àwọn ènìyàn gbogbo kò ti ìfòpin sí ìṣọdẹ-àjẹ́ lẹ́yìn. Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́-ènìyàn tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ kí á mọ̀ wípé àbùkù ìrànwọ́ ìjọba àti àwọn onímọ̀ ni kò mú ìwà àìbójúmu náà ṣíra kásẹ̀ ńlẹ̀. Ohun tí ó dára jù lọ ni wípé àwọn tí ó ń tako ìwà burúkú yìí gbàgbọ́ wípé àyípadà lè dé. Ní ọ̀rọ̀ọ Prem Chand: Akitiyan láti f’òpin sí ìṣọdẹ-àjẹ́ lè tẹ̀lé ìlànà tí ìjọba fi polongo ètò mímọ̀ọ-kọ-àti-mímọ̀ọ-kà. Bákan náà, àwọn onímọ̀ ní láti f’ọwọ́ sí i k’áwọn ènìyàn ó ba f’ohùn sí i. Ìṣọdẹ-àjẹ́ jákèjádò India Jharkhand ti ṣe àkọsílẹ̀ iye ẹṣẹ̀ àwọn ènìyán ṣẹ̀ tí ó pọ̀ jù lọ tí ó tan mọ́ ìṣọdẹ-àjẹ́ àmọ́ kì í ṣe ìpínlẹ̀ náà nìkan. Ọ̀ràn-an ìṣọdẹ-àjẹ́ ti wà l’ákọsílẹ̀ ní Chattisgarh, Odisha, Gujarat, West Bengal Assam, Bihar, Maharashtra àti Rajasthan pẹ̀lú. Nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní 2014, Debjani Bora, ẹlẹ́sẹ̀ ehoro ọmọ bíbíi orílẹ̀-èdèe India ti fi ara kááṣá rí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ọ Debjani, a f’ẹ̀sùn-un ìgbẹ̀mí ènìyàn púpọ̀ kàn án ní abúlée Cherekali tí ó wà ní kìlómità 180 láti Guwahati, olú-ìlúu India ti apáa ìlà-oòrùn. Olóríi gbọ̀gán àdúrà abúlé l’ó dárúkọ rẹ̀ tí àwọn ará abúlé sí fi ìyà jẹ́ ẹ. Ìṣẹ̀lẹ̀ 2017 ní ipínlẹ̀ Rajasthan. Lára èyí ni, ọmọbìnrin ogójì ọdún kan Kanya Devi rí ìkọlù tí a sì lù ú pa lẹ́yìn tí mọ̀lẹ́bíi rẹ̀ fi ẹ̀sùn kàn án ní agbègbèe Ajmer. Bí àpamọ́ àlọ́ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ ṣe mú ọ̀rọ̀ àyíká di mímọ̀ ní Mekong Ní ọdún 2014, ogunlọ́gọ̀ ìbílẹ̀ ní Mekong bẹ̀rẹ̀ sí ní í ṣe àkọsílẹ̀ àwọn àlọ́ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ wọn pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹgbẹ́ aṣèwádìí kan tí ó ń ṣe àyẹ̀wò fínnífínní sí bí ìtàn wọ̀nyí ṣe lè ṣe ìrànwọ́ tí yóò tú àṣìírí ìmúdìbàjẹ́ àyíká tí àwọn iṣẹ́ ńláǹlà ń fà ní agbègbè náà. Mekong jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn odò ńlá Ásíà tí ó ṣàn gba orílẹ̀-èdè mẹ́fà: China, Myanmar, Thailand, Laos, Cambodia, àti Vietnam. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ ìṣẹ̀dá abẹ̀mí àti ewéko tí ó jẹ́ ohun ìsayéró fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbẹ̀ àti apẹja. Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ńláǹlà bíi kòtò ìdarí-omi ṣíṣàn fún Ìpèsè Iná Mànàmáná ti lé àwọn olùgbé jìnà ó sì ń ṣe àkóbá fún nnkan ìṣẹ̀dá odò náà. Ọ̀kanòjọ̀kan ìfẹ̀hànnúhàn kò ṣe nǹkan kan, àwọn iṣẹ́ ìdarí-omi ṣíṣàn ṣì ń lọ, pàápàá jù lọ ní Laos àti Thailand. Pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Mekong Watch, ẹgbẹ́ kan ní Jápáànì ń jà fún ìdàgbàsókè ní agbègbè náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbà ní Mekong ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ wọn tí ó ní íṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀dá. Mekong Watch gbàgbọ́ wípé àwọn ìtàn wọ̀nyí “ti kó ipa ribiribi ní ti ìdáàbò ìṣẹ̀dá nípa dídẹ́kun ìwà àìbìkítà fún ọrọ̀ ìṣẹ̀dá.” Mekong Watch sọ wípé ohun ìṣẹ̀dá nìkan kọ́ ni a ní láti dáàbò bò àmọ́ àti àwọn “nǹkan àjogúnbá tí-a-kò-le-è-rí-dìmú” tí a lè pín àti rí lò. Toshiyuki Doi, olùdámọ̀ràn àgbà fún Mekong Watch, ní èyí láti sọ: Ó pọn dandan fún wa láti ka ìtàn àwọn ènìyàn Mekong kún, kí a dá wọn mọ̀, àti bọ̀wọ̀ fún wọn, papàá jù lọ ní òde òní tí wọ́n ti ń pàdánù àyè wọn ní ìrọ́pò ilé iṣẹ́ oníròyìn ìgbàlódé, tí wọn kò sì fi àjogúnbá lé ìran tí ó ń bọ̀ lọ́wọ́. Ẹgbẹ́ náà ṣe gudugudu méje yàyà mẹ́fà kí ó tó kó oríṣiríṣi ìtàn 102 jọ ní Cambodia, Laos, àti Thailand. A ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìtàn wọ̀nyí, dà á kọ sílẹ̀ sínú ìwé, àti ìtúmọ̀ ìtàn sí àwọn èdè orílẹ̀ Thailand, Laos, àti Cambodia kí ó tó kan ẹ̀da ti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Mekong Watch tẹ àwọn ìtàn wọ̀nyí jáde sórí ìwé ìròyìn pélébé àti sórí ẹ̀rọ ayárabíàṣá, wọ́n sì tún lò ó ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa àyíká ní àwọn ìlú náà. Àwọn agbègbè ní Mekong níbi tí àwọn oníṣẹ́-ìwádìí ti ṣe iṣẹ́. Kmhmu’ ní àríwá àti àárín gbùngbùn Laos;; Siphandon ní gúúsù Laos; Akha ní àríwá Thailand; Thai So atí Isan ní àríwá-ìwọ̀-oòrùn Thailand; Bunong ní àríwá-ìwọ̀-oòrùn Cambodia. A lò ó pẹ̀lú àṣẹ. Láti ìparí ọdún 2016, a ti fi ìtàn àwọn ènìyàn ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àyíká fún àwọn èwe ní ìgbèríko Laos àti Thailand. A ti ṣe àgbékalẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìwé àti ní ìlú ìbílẹ̀ láti tọ́ àwọn èwe sọ́nà, àti àwọn àgbà nígbà mìíràn, láti ṣe àkọsílẹ̀ ìtàn ẹnu àwọn àgbàlagbà, fi ìtàn náà kọ́gbọ́n, àti láti sọ wọ́n di kíkà. Àpẹẹrẹ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan ni ìtúnsọ àlọ́ ‘Òwìwí àti Àgbọ̀nrín‘ àwọn aráa Kmhmu ní àárín gbùngbùn àti àríwá Laos. Àlọ́ náà dá lóríi òwìwí tí kò ríran ní ọ̀sán nítorí ó yan àgbọ̀nrín jẹ. Níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan, a bi àwọn èwe tí ó kópa: “Irúfẹ́ ẹranko wo ni a bá nínú àlọ́ náà?”, “Ǹjẹ́ a lè rí àwọn ẹranko wọ̀nyí ní abúlée yín bí?”, àti”bóyá àwọn ẹranko wọ̀nyí ti dínkù sí ti ìgbà kan, kí ni ìwọ rò wípé ó ti ṣẹlẹ̀?” Lẹ́yìn èyí, a gba àwọn akópa ní ìyànjú láti so àlọ́ náà mọ́ ìdìbàjẹ́ àyíká ní ìlúu wọn. Ní agbègbè Champasak, gúúsù Laos, ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ ẹranko omi tí ó ti ń dínkù Irrawaddy dolphin àti ẹyẹ Sida ni a ń lò fi ṣe àpèjúwe bí iṣẹ́ ìdarí-omi-ṣíṣàn ṣe ń ṣe àkóbá fún ẹja inú odò Mekong. Àlọ́ mìíràn láti gúúsù Laos ní àwọn ìlànà tí ó kọ́ni nípa ìmọrírìi ìbójútó ọrọ̀ ìṣẹ̀dá: Ní ìgbà kan, ológun kan wọ inú igbó iwin kan. Ó ṣe alábàápàdé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewé kátabá níbẹ̀ ó sì ṣẹ́ wọ́n. Àmọ́ ṣá, bí ó ti fẹ́ẹ́ jáde nínú igbó náà, ọ̀nà dí mọ́n ọn ní ojú, kò sì mọ ọ̀nà mọ́. Nítorí wípé ó ṣẹ́ ewé kátabá tí ó pọ̀ ju èyí tí ó lè lò lọ ni kò fi mọ ọ̀nà mọ́n. Ó wá ọ̀nà títí kò rí. Ẹ̀rí-ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ́ ẹ fún ohun tí ó ṣe, ó pinnu láti dá àwọn ewé kátabá náà padà sí ibi tí ó ti gbé ṣẹ́ ẹ. Wéré tí ó sọ ọ́ sílẹ̀, logan ni ó rí ọ̀nà ní iwájúu rẹ̀. A ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ Orí Erinmi ní ọjọ́ 16, oṣù Belu, ọdún 2014, ní etídò Songkran ní àríwá-ìwọ̀-oòrùn Thailand. Mun Kimprasert, ẹni ọdún 68. ni asọ̀tàn. Mekong Watch ló ni àwòrán, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ. Ní àríwá Thailand, àlọ́ àwọn aráa Akha kan nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ swing tí ó sọ iṣẹ́ takuntakun ìfaraẹnisílẹ̀ t'ẹ̀gbọ́ntàbúrò tí ó mú ayé rọrùn. Ní àríwá ìwọ-oòrùn Thailand, àlọ́ kan tí ó dá lórí Ta Sorn tí Tongsin Tanakanya sọ ṣe ìgbélárugẹ ìṣọ̀kan láàárín aládùúgbò ní ìlú iṣẹ́ àgbẹ̀. Ìtàn mìíràn ṣe ìrántí bí pípa àgbànrere kan ṣe fa iyọ̀ títà ní apá orílẹ̀-èdè yìí. Ní Bunong, tí ó wà ní àríwá ìwọ-oòrùn Cambodia, àwọn àlọ́ tí ó sọ nípa ètùtù fún àtúnṣe sí ìgbéyàwó tí kò ní adùn àti ètùtù ìfọ́nrúgbìn àti ìkórè tí Khoeuk Keosineam jẹ́ asọ̀tàn. Bákan náà ni ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ erin tí Chhot Pich sọ ṣe àfihàn bí àwọn òrìṣà ṣe sọ àwọn ará abúlé tí ó fi májèlé sí inú odò di erin. Ó sọ ìdí tí ó fi rọrùn fún erin láti máa gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn àmọ́, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran, wọ́n gbàgbé ìpìlẹ̀ wọn, wọ́n lọ ń gbé nínú igbó. Fún Mekong Watch àti àwọn agbègbè ní ìlú náà tí àkóbá ti bá, ìpamọ́ àwọn ìtàn wọ̀nyí ṣe kókó nínú ìpolongo ìkọjú-ìjà sí àwọn iṣẹ́ tí yóò lé ẹgbẹẹgbẹ̀rún olùgbé Mekong kúrò ní ilée wọn: Ìtàn wọ̀nyí lè di ìdánimọ̀ọ wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìlú àti ìbáṣepọ̀ t'ó dán mánrán pẹ̀lú àyíká. Nípasẹ̀ẹ ìtàn, ìlú yóò wá ọ̀nà ìgbàmọ́ra àti/tàbí ìkọjú-ìjà sí ìyípadà tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní odò Mekong. China fi ọwọ́ọ ṣìnkún òfin mú ayàwòrán eré orí ìtàgé nítorí pé ó tún àwòrán ìgò ọtí-líle kan tí ó ń tọ́ka sí Ìpanìyànnípakúpa Tiananmen pín Jennifer Creery ni ẹni tí ó kọ ìròyìn yìí, tí Ilé Iṣẹ́ Atẹ̀wé Olómìnira Hong Kong sì tẹ̀ ẹ́ jáde ní ọjọ́ 24 oṣù Èbìbí ọdún-un 2019. Ohùn Àgbáyé ṣe ẹ̀dàa ìròyìn náà ní abẹ́ ìtọwọ́bọ̀wé àjọṣe pọ̀ ìkóròyìnjọ. Àwọn aláṣẹ ìjọba China ti fi ayàwòrán eré aṣakọ̀sílẹ̀-ìṣẹ̀lẹ̀ Deng Chuanbin sí àtìmọ́lé lẹ́yìn tí ó ṣe túwíìtì àwòrán ìgò ọtí-líle kan tí a sààmìi “64” sí lára – tí ó ń tọ́ka sí ọjọ́ burúkú Èṣù gbomi mu Ìpaninípakúpa tí ó wáyé ní Tiananmen Square ní ọjọ́ 4, oṣù Òkúdù ọdún-un 1989. Ìgò ọtí-líle 64 Ọdún-un 2016 ni a ṣe ìgòo ọtí-líle náà, ìyẹn ní ìrántí ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi ọjọ́ 4 oṣù Òkúdù wáyé. Orúkọ tí a pe ọtí-líle náà ni “8 wine 64″. Bí a ti ṣe ń pe “wine” ní èdèe Putonghua náà ni à ń pe “9”. Ààmì ara ìgò náà ní àwòrán “Ọkùnrin ọkọ̀-ogun” tí a kọ “Máà ṣe gbàgbé, máà ṣe sọ̀rètí nù”. Ó sì tún fi han gbangbagbàngbà pé Beijing ni a ti ṣe ọtíi wáìnì náà tí ó ní ìdá 64 iye ọtí-líle nínú tí ó sì ti wà nílé ìtajà fún ọdún mẹ́tadínlọ́gbọ̀n. A fi ọwọ́ọ ṣìnkún òfin mú àwọn ọmọkùnrin orílẹ̀ èdèe China mẹ́rin, Fu Hailu, Zhang Jinyong, Luo Fuyu àti Chen Bing, ní ọdún-un 2016 fún ìṣẹ̀lẹ̀ ìgò ọtí-líle tí a sì fi ẹ̀sùn-un “rírú ìṣẹ́po agbáraiìlú sókè”. Ìgbẹ́jọ́ Fu, Zhang àti Luo's wáyé ní ibìkan ní Ilé-ẹjọ́ Àwọn Ènìyàn Agbedeméjì Chengdu nínú oṣù Igbe. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gba ìdájọ́ ìgbà ọdún mẹ́ta ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú ìdádúró ọdún mẹ́rin sí márùn-ún. Nítorí pé Chen kò gbà wípé òun dá ẹ̀ṣẹ̀, ó sì wà lábẹ́ẹ ṣìgún òfin. Pẹ̀lú ìdádúró ìrànlẹ́wọ̀n, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣì wà lábẹ́ ìṣọ́: Ìfọwọ́ọ ṣìnkún òfin múni nítorí àtúnpín túwíìtì Ní ìpalẹ̀mọ́ ìsààmì ọgbọ̀n ọdún tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ 4, ayàwòrán eré orí ìtàgé Deng Chuabin ti di ẹni tí ọ̀rọ̀ ìgò ọtí-líle 64 ń dá sẹ̀ríà fún lọ́wọ́lọ́wọ́. Ọlọ́pàáa Sichuan fi ọwọ́ọ ṣìgún òfin mú Deng ní ilée rẹ̀ ní Yibin ní ọjọ́ Ẹtì tí ó kọjá, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ó ṣe àtúnpín àwòrán-an Twitter kan tí ó jẹ́ ti ìgò ọtí-líle 64, gẹ́gẹ́ bí Iléeṣẹ́-tí-kìí-ṣe-tìjọba, Adáààbòbo Ẹ̀tọ́ Ọmọ ènìyàn ti China (CHRD). Ayàwòrán náà gba ìpè àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn-in ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lẹ́yìn tí ó túwíìtì àwòrán náà pẹ̀lú wípé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó mú un wálẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni CHRD ṣe ti sọ. Àwọn ọlọ́pàá fi agbára gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká mẹ́ta, ẹ̀rọ ayárabíàṣá kọ̀mpútà kan, ẹ̀rọ ayárabíàṣá àgbélétan kan, iPad, ike pélébé ìrántí àti ẹ̀rọ ayàwòrán kékeré kan nígbà tí wọ́n wá sí ilée rẹ̀. Deng ti wà ní Àtìmọ́lé Agbègbè Nanxi nítorí wípé “ó ń bá ìjà bọ̀” – ẹ̀sùn tí wọ́n sábà máa ń kà mọ́ àwọn ènìyàn tí ó ń takò ìjọba lẹ́sẹ̀. CHRD sọ wípé fún wákàtí kan gbáko, àwọn ọlọ́pàá padà láti yẹ ilée Deng wò, wọ́n sì kó àwọn ẹ̀rọ lóríṣiríṣi: Ọ̀rọ̀ tí ó ń lọ nípa Deng Chuabin: Ní ọjọ́ 20 oṣù Èbìbì ọdún-un 2019: Àwọn ọlọ́pàá àgọ́ọ Peizhi ránṣẹ́ sí bàbáa Deng. Àwọn kan tẹ̀lée padà sílé, wọ́n sì ya àwòrán nínú ilée wọn. Wọ́n tú yàráa Deng Chuabin wò fún bíi wákàtí kan, wọ́n sì gbé ẹ̀rọ 20 àti agbaná sí ara ẹ̀rọ. Wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n mú okùn ìkòkò ìse-ìrẹsì. Ní ọjọ́ 21, àwọn ọlọ́pàá sọ fún àwọn òbíi Deng láti máà gba agbẹjọ́rò fún un. Deng, tí a tún mọ̀ sí Huang Huang, tí ó jẹ́ ayàwòrán aládàádúró tí ó ti bá òǹyàwòrán Beijing, Ai Weiwei ṣiṣẹ́ papọ̀. Ó sọ wípé òun ti ní ìdojúkọ ìjọba, pẹ̀lú àtìmọ́lé ní ọdún-un 2015 láti dénà dè é kí ó máà lọ sí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní Geneva. Oṣù tí ó ń bọ̀ ni ó sààmì ọgbọ̀n ọdún tí ìpaninípakúpa Tiananmen Square wáyé. Lọ́dọọdún, àwọn aláṣẹ China fi ọwọ́ agbára mú ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí wọ́n sì fi àwọn agbọ̀rọ̀dùn sí àtìmọ́lé. Pẹ̀lú ìdásílẹ̀ àwọn akọ̀ròyìn-in Reuters, ẹ̀ṣẹ̀ ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ṣì jẹ́ ní Myanmar Akọ̀ròyìn Reuters méjì Wa Lone àti Kyaw Soe Oo rìnrìn òmìnira lẹ́yìn tí a dá wọn sílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n Insein ní Yangon. Àwòrán àti ọ̀rọ̀ abẹ́-àwòrán láti ọwọ́ọ Myo Min Soe / Irrawaddy náà ń bá Ohùn Àgbáyé ṣiṣẹ́ ìròyìn. Àwọn ẹgbẹ́ iléeṣẹ́ oníròyìn àti ajà-fún-ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ń ṣe àjọyọ̀ọ ti ìdásílẹ̀ lẹ́wọ̀n-ọn akọ̀ròyìn Reuters Wa Lone àti Kyaw Soe Oo tí ó lò ju ọjọ́ 500 ní àtìmọ́lé fún ipa tí wọ́n kó nínú ìwádìí òfíntótó ìṣẹ̀lẹ̀ ìpanípakúpa àwọn olùgbée Rohingya kan ní gúúsù Myanmar. Àmọ́ pẹ̀lú ìdásílẹ̀ tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, ipò yẹpẹrẹ ni òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní ìlú náà nítorí wípé ìtìmọ́lé àti ìfìyàjẹ àwọn akọrin, akọ̀ròyìn, àti ajìjàǹgbara ṣì wà síbẹ̀ sẹpẹ́. Ka àwọn ọ̀ràn ìsàlẹ̀ yìí síwájú: Ìfẹ̀sùn Ìbanilórúkọjẹ́ kan Irrawaddy Náà Ẹ̀ka ológun Agbègbè Yangon kọ ìwé ẹ̀sùn-un ìbanilórúkọjẹ́ sí olóòtú èdèe-Burmese U Ye Ni wípé ibùdó-ìtakùn-àgbáyé akọ̀ròyìn náà gbè lẹ́yìn ẹnìkan nínú ìròyìn ìkọlù láàárín-in ọmọ-ogun ìjọba àti àwọn adárúgúdù sílẹ̀ Ọmọ ogun Arakan ní Ìpínlẹ̀ Rakhine tí ó tẹ̀ jáde. Irrawaddy Náà sọ wípé òun kò ṣe àṣemáṣe ju jíjábọ̀ọ ìwọ̀yáàjà tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní sàkání náà láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún-un 2019. Èsì tí U Ye Ni fún àwọn ọmọ ajagun rè é : Ó ká mi lára nípé iṣẹ́ẹ wa kò yé ikọ̀ ajagun yékéyéké. Nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn ni ó ti fi lélẹ̀ wípé a gbọdọ̀ tànmọ́lẹ̀ sí ìjìyà àwọn ènìyàn ní ibi tí rògbòdìyàn bá wà. Èròńgbà wa tí a fi tẹ̀lé ìròyìn náà ó ju láti fa àkíyèsí àwọn tí yóò tán ìṣòro sí ìjìyà àwọn ènìyàn. Àjọṣepọ̀ tí ó dán mọ́nrán ń bẹ ní àárín-in Ohùn Àgbáyé àti Irrawaddy. Àjùsẹ́wọ̀n fún yẹ̀yẹ́ Ìyẹn bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ẹ ajótà Ìran Ọ̀kín Thangya márùn-ún di èrò ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní Insein títí di ìgbà tí wọn yóò lọ sí ilé ẹjọ́ fún ẹ̀fẹ̀ tí wọ́n fi ológun ṣe. Eré ìtàgé tí ó ní àkójọpọ̀ orin abínibí, ijó àti ewì ni a mọ Thangyat mọ́. Ẹ̀gbẹ́ alájòótà yìí ti tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin abala 505(a) tí ó ní wípé ọ̀daràn ni ẹni tí ó bá polongo ọ̀rọ̀, àyesọ, tàbí jábọ̀ irúu rẹ̀ pẹ̀lú èrò láti mú kí ikọ̀ ajagun ó máà ka ojúṣe rẹ̀ kún tàbí kùnà láti ṣe ojúṣee rẹ̀. Ọ̀kan lára ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn, Zeyar Lwin, sọ pé: Gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá jẹ́ ti òṣèlú torí ìdí èyí ó yẹ kí wọ́n ṣe àtúnṣe gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rọ̀ òṣèlú. Bákan náà, mo máa sọ wípé gbogbo wa ní láti darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ àtúnṣe sí ìwé òfin ọdún-un 2008 tí ó ń lọ lọ́wọ́ nínú ìgbìmọ̀ ìjọba. Ní tèmi, gbogbo ọ̀ràn yìí pátá yóò jẹ́ yíyẹ̀ lulẹ̀ bí a bá le è ṣe iṣẹ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ ti àtúnṣe sí ìwé òfin. Zeyar Lwin ń tọ́ka sí ìwé òfin ọdún-un 2008 tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn atúnǹkanká gbàgbọ́ wípé a ṣe é to láti fi agbára fún ìṣèjọba ikọ̀ ajagun pàápàá lẹ́yìn tí alágbáda gba ìjọba. Aya-eré-ìtàgé aláàárẹ̀ nínú àtìmọ́lé Ọ̀ràn aya-eré-ìtàgé Min Htin Ko Ko Gyi tún fi ìrísí ìhámọ́ tí a há àwọn akọrin pàtàkì mọ́. Ìwé ẹ̀sùn tí ọ̀físà jagunjagun kọ nípa àwọn àtẹ̀jáde ‘ìbanilórúkọjẹ́’ tí aya-eré-ìtàgé gbé sí orí Facebook tí ó fà á tí a fi fi òfin mú un. Min Htin Ko Ko Gyi ni olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ Àjọ̀dún Eré Ajàfẹ́tọ̀ọ́ Iyì Ọmọnìyàn àti ìlúmọ̀nánká alátakò ìlọ́wọ́sí ikọ̀ ajagun nínú òṣèlú. Àwọn alátìlẹ́yìn-in rẹ̀ ń pè fún ìtúsílẹ̀ẹ rẹ̀ lóríi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, látàrí wípé a ti yọ àbọ̀ ẹ̀dọ rẹ̀ nítorí àrùn jẹjẹrẹ àti àrùn ọkàn àti ìṣòro kíndìnrín. Àjọṣe Eré Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, tí ó jẹ́ àjọṣepọ̀ àjọ̀dún eré ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn 40 kárí ayé, fi lẹ́tà ṣọwọ́ sí ìjọba: Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ajìjàǹgbara àgbáyé tí ọ̀rán kàn, a tọrọ ìdánilójú ìjọba Myanmar láti ríi dájú wípé Abala 66 (d), tí ó yẹ kí ó sún ìtẹ̀síwájú ẹ̀rọ ayárabíàṣá síwájú, tí kò ní jẹ́ lílò fún ìpalẹ̀mọ́ ọmọ ìlúu Myanmar tí ó fẹ́ sọ èròo ọkàn-an wọn àti lọ́wọ́ sí ètò ìṣèlú ìjọba àwa-arawa ní Myanmar. Lẹ́tà náà tọ́ka sí ti àríyànjiyàn Abala 66(d) tí ó sọ nípa òfin ìbánilórúkọjẹ́ tí àwọn aláṣẹ ń lò láti to fi ẹ̀sùn ìtakò, ìjìjàgbara, àti akọ̀ròyìn. Ilé ẹjọ́ ìbílẹ̀ kọ ìwé ẹ̀dùn tí Min Htin Ko Ko Gyi kọ fún béèlì. Ìgbẹ́jọ́ọ rẹ̀ tún di ọjọ́ 9, oṣù Èbìbì ọdún-un 2019. “Kò yẹ kí wọ́n di èrò ẹ̀wọ̀n ní ìbẹ̀rẹ̀.” A rán Wa Lone àti Kyaw Soe Oo sí ẹ̀wọ̀n ọdún méje fún rírú òfin Ìkọ̀kọ̀ sáà-akónilẹ́rú. Ilé Ẹjọ́ Àgbà di ìdálẹ́jọ́ tí wọ́n ṣe ní oṣù Igbe tí ó kọjá àmọ́ a dá wọn sílẹ̀ lẹ́yìn ìdáríjì ààrẹ ní àsìkò Ọdún Tuntun ìbílẹ̀ orílẹ̀ èdè náà. Àwọn ẹgbẹ́ bíi Southeast Asian Press Alliance kí Wa Lone àti Kyaw Soe Oo káàbọ̀ lẹ́yìn-in tí a dá wọn sílẹ̀ àmọ́ wọ́n sọ ìyànjẹ tí ó kojú àwọn akọ̀ròyìn méjèèjì: Kò yẹ kí wọ́n di èrò ẹ̀wọ̀n ní ìbẹ̀rẹ̀, nítorí wọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n. Nígbàtí a gba ìdàgbàsókè yìí wọlé, ẹjọ́ọ Wa Lone àti Kyaw Soe Oo jẹ́ ẹ̀rí wípé ẹ̀mí àwọn akọ̀ròyìn tí ó ń ṣe àyẹ̀wò sí ìṣèlú wà nínú ewu ìgbẹ̀san òṣèlú. Olórí orílẹ̀-èdè Azerbaijan tàkùrọ̀sọ àkọ́kọ́ ní orí amóhùnmáwòrán lẹ́yìn ọdún 15 ní orí àlééfà. Ó lè lo ọ̀nà mìíràn. Ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ Ààrẹ Ilham Aliyev àti amóhùnmáwòran REAL TV ní Oṣù Èrèlé 12. Àpá àwòrán wá láti REAL TV ẹ̀rọ-alátagbà Ẹ̀rìn mélòó ló yẹ kí ààrẹ orílẹ̀ èdè ní ìtakùrọ̀sọ pẹ̀lú ilé ìgbéròyìn jáde tí ìlúu rẹ̀? Ẹẹ̀kan l'ọ́sẹ̀? Ẹẹ̀kan l'óṣù? Àwọn olórí orílẹ̀ èdè afipá ṣe ìjọba máa ń ṣe ìtakùrọ̀sọ pẹ̀lú àwọn ilé ìgbéròyìn jáde ní èèkàn l'ọ́dún tàbí kí ó kéré jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí kọyọyọ ní Azerbaijan. Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, Ààrẹ Ilham Aliyev, tí ó di olórí ilẹ̀ Azerbaijan ní Oṣù Ọ̀wàrà ọdún 2003, ṣe ìtakùrọ̀sọ alákọ̀ọ́kọ́ọ rẹ̀ pẹ̀lú ilé ìṣẹ́ amóhùn-máwòrán ti ìlúu rẹ̀. Ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò oníwákàtí kan ọ̀hún tí ó wáyé lọ́jọ́ 12 oṣù yìí, pẹ̀lú oníròyìn ìjọba Mirshahin Aghayev tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí fún ìdúróṣinṣin aìfi òlò p'ohùn di gbígbésáfẹ́fẹ́ ní ilé ìṣẹ́ amóhùn-máwòrán aládàáni agbè fún ìjọba REAL TV. Ó gbọn òǹgbẹ ni Azerbaijan, ilẹ̀ tí àwọn ará ìlú ti máa ń gbọ́ kí Aliyev sọ̀rọ̀ lórí afẹ́fẹ́, àmọ́ tí wọn kò sì rí i rí kó tàkùrọ̀sọ pẹ̀lú oníbèèrè. Kódà ìṣàmúlò Twitter Aliyev dà gẹ́gẹ́ bí wèrè aládàásọ̀rọ̀ ju ìgbìyànjú ìbá ará ìlú sọ̀rọ̀ lọ. Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò ọ̀hún jẹ́ àkọ́ṣe tí ó kọyọyọ. Púpọ̀ àwọn tí ó wà lórí ẹ̀rọ ayélujára gbogbo sọ̀rọ̀ lórí aìkọbì-ara sí bí ààrẹ ṣe gbé ara rẹ̀, bí ó ṣe múra àti àwọn kókó tí ilé ìṣe ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ ìjọba sọ̀rọ̀ lé lórí. Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé kò pọn dandan kí Aliyev ṣàfihàn ara rẹ̀ bí ó ṣe tó Azerbaijan kòì tí ì dìbò tí kò sí kọ́mí-n-kọ́họ lẹ́yìn ọdún 37 tí ó ti gba òmìnira kíni ó mú u ṣe èyí? Àwọn kókó ìtakùrọsọ ọ̀hún dá lórí ìjàkú akátá pẹ̀lú Armenia lóríi Nargono- Karabakh, iṣẹ́ ìlú, àtúnṣe sí ètò ọrọ̀ Ajé, àti ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ẹgbẹ́ Aláṣẹpọ̀ Eurasian àti Ẹgbẹ́ Aláṣẹpọ̀ Europe. A kò rí ohun tuntun kan gbámu. Lẹ́yìn ìgbà tí fídíò ọ̀hún gba kòbákùngbé ìjábọ̀ bíi “Kọ̀wé fipò sílẹ̀” àti “A kò fẹ́ àlọ́ atanijẹ mọ́” pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìní ìfẹ́ràn ní ọjọ́ àkọ́kọ́ tí a gbé e sórí ayélujára, ìkànnì REAL TV ní oríi YouTube ti ìsọsí pa. Olóṣèlú alátakò Azer Gasimli sọ pé ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò ọ̀hún fi hàn pé “ìfoyà ti dé bá” ìjọba láàárín bí àwọn ará ìlú ò ṣe gba ti wọn àti ọ̀rọ̀ ajé ìlú tí ó ń ṣ'òjòjò. Mo wo ìtàkùrọsọ àkọ́kọ́ tí Ilham Aliyev ṣe pẹ̀lú oníròyìn ilẹ̀ yìí kan. Mo rò pé kò mọ́gbọ́n dání láti sọ tàbí kọ nǹkan kan l’ ésì si ohun tí Ààrẹ sọ. Nítorí pé a ti ń fún un l'ésì fún ọdún pípẹ́. Kò sí hóró òótọ́ kán nínú ìtàkùrọsọ ọ̀hún. Ààrẹ àti oníròyìn ọ̀hún rán mi l'étí nípa “ọkọ̀ tó léfòó lórí irọ́”. Ní àkótán: ara ò rọ ìjọba! Habib Muntazir, aládàádúró oníròyìn kan fi ẹ̀dùn ọkàn-an rẹ̀ hàn pé ìtàkùrọsọ ọ̀hún kò gbóòkàn: Nǹkan kan ṣo tí mo gbọ́ ni “Ìyá àgbà Saray”. Ó dá mi lójú pé ” Ìyá àgbà” yìí yóò ṣòro tí ó wúni lórí ju Ilham Aliyev lọ. Ìfakùn ọ̀rọ̀ “Ìyá àgbà Saray” tí Muntazir mẹ́nubà dá lórí àbẹ̀wò ìbánidárọ tí Aliyev bá lọ sí Agbègbè Shamakhi tí Azerbaijan, níbi tí ìporùrù ayé tí bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ìgbé jẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, tí ọ̀kan nínú rẹ̀ jẹ́ ti obìrin ọlọ́mọdún 92 tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Saray. Ajábọ̀ iṣẹ́ ìjọba ti fúnpá lórí ìpàdé tí Aliyev ní pẹ̀lú Saray, ẹni tí ó ti gba oríyìn gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe rere fún ìfaradà àti ìgbàgbọ́ tí ó ní sí ọjọ́ iwájú orílẹ̀-èdè Azerbaijan lẹ́yìn-in ìṣẹ́lẹ̀ náà. Bí a ṣe lè ri lára ìtú ìmọ̀ ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ REAL TV l'órèfé, Aliyev sọ àsọdùn ọ̀rọ̀ nínú ìgbóríyìn fún arúgbó ọ̀hún, bí ò tí ṣe perí rẹ ní sísẹ̀ntẹ̀lé: Irú ìyá àgbà àti àwọn ìyá, gẹ́gẹ́ bíi Ìyá àgbà Saray ti ń ṣakitiyan ìpamọ́ àwọn ìṣe orílẹ̀ wa àti ẹ̀mí-àìrí fún àìní ye ọgọ́rùn-ún ọdún. Gbogbo obìnrin Azerbaijan ni ó fẹ́ fi ìwà jọ ìyá àgbà Saray. Wò ó, obìrin ọmọ ọdún 92 èyí tí ilé rẹ̀ ti di ìlẹ̀ẹ́lẹ̀, ìrètí gidi wo ló tún wà fún un mọ́! Ìyá àgbà Saray ní ìfọkàntẹ̀ pé ìjọba yóò dúró tì òun. Kámáparọ́, nínú ìrìnàjò kékeré lọ sí Shamakhi, n kò rò ó tì tẹ́lẹ̀ pé n ó ṣe àlábàpáàdé Ìyá àgbà Saray. Mo yẹ àwọn ilé tí ìporùrù ilẹ̀ ọ̀hún bà wò fínnífínní, mo sì rí àrító ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ tí mo rí Ìyá àgbà Saray, àrídájú mi lórí bí àwọn ọmọ Azerbaijan ṣe ṣ'èèyàn sí l'ékún sí i. Àwọn ọmọ ilẹ̀ wa á máa mú ìwúrí báni. Ó wà nínú ìṣòro; ilée rẹ̀ ti wó. Ó jọ pé kò mọ̀ pé ẹnìkan yóò wá ṣe ìrànwọ́ fún òun. Kò mọ̀ bóyá ilé òun yóò dí àtúnkọ́ tàbí wọn yóò dà á wó pátápátá kọ́ òmíràn. Àwọn ìyá àgbà bíi Saray ní ẹ̀mí ìforítì òun ìlọra tí ó mú àwọn ọmọ Orílẹ̀ Azerbaijan yàtọ̀. Oníròyìn aládàádúró mìíràn, Sevinc Osmangizi, fi ṣe àgbékalẹ̀ ìpè kan ní oríi YouTube tí ó ń pè fún ìda-ọ̀rọ̀-wo lórí ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwo ọ̀hún lẹ́yìn tí Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ parí. Àwọn tí wọ́n wò ó sọ àwọn nǹkan tí kò tẹ́ wọn lọ́run, wón sì tún pè fún àyípadà. Ọ̀kan ní: N kò le è wo ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ náà ju ibi mo wò ó dé lọ, mo sì pa ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán. Nítorí pé, òfé lásán ni olùbéèrè Mirshahin Aghayev àti ìbéèrè rẹ̀. Àdéhùn wọn kò wúlò fún wa mọ́. Èké àti irọ́ wọn ti sú àwọn èèyàn. Àwọn ará ìlú ń fẹ́ ohun tuntun àti àtúntò tòótọ́. Jẹ́ kí àwọn òkú ó sọ ìtàn nípa Hong Kong Ìkìlọ̀: ìròyìn yìí ní àwọn àwòrán tí ó ń ṣe àfihàn ikú àti ipá. Medium ti ṣe àtẹ̀jáde ẹ̀dàa ìr��yìn yìí ṣáájú èyí. Bí o bá ti rìnrìn àjò lọ sí Hong Kong, o ṣe é ṣe kí o dé Yau Ma Tei, agbègbè ọjà alẹ́ tí ó jẹ́ ìlúmọ̀nánká níbi tí àwọn ènìyàn ti máa ń lọ ra ọjà àti oúnjẹ ẹ̀gbẹ́ẹ títì. Yau Ma Tei jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbègbè tí èró pọ̀ sí jù lọ ní Hong Kong. Láti ọdún-un 2016, ẹ̀ka- ìlú náà ti di ibùdó fún “20,000 ọ̀nà láti gbà kú ní Yau Ma Tei”, ìtọ́nà “ìrìnàjò afẹ́ ìpànìyàn” tí Melody Chan àti èmitìkarami ṣe olùdásílẹ̀, tí ó ti ń gbé àdúgbò náà fún ọdún púpọ̀. Nípasẹ̀ ìrìnàjò afẹ́ náà, a fẹ́ mọ bí ayé àti ìgbé ayé ṣe rí ní Hong Kong. Ìrìnàjò afẹ́ ojúnà oní kìlómítà 1.5 náà lọ láti arẹwà àti gúúsù Yau Ma Tei, àti ìrìnàjò dé ibi tí a ti pa ènìyàn 12 ní àárín-in wákàtí méjì. A bẹ̀rẹ̀ ẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ètò Halowíìnì láti kó owó jọ fún ilé-iṣẹ́ ìbílẹ̀ kan. Èsì tí a gbà dára tó bẹ́ẹ̀ ni ó mú wa tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò alẹ́ nínú oṣù tí yìnyín bá ń bọ́ tí ojú ọjọ́ bá tútù. Oníṣẹ́ ìlú ni àwọn amọ̀nà, olùkọ́, oníṣègùn àti àwọn onímọ̀ mìíràn. Bí a bá kà á ní ẹníméjì, ó ti tó ènìyàn 500 tí ó ti ṣe ìrìnàjò náà. Àwọn ọ̀ràn ìpànìyàn tí a yàn wáyé ní àárín-in ọdún-un 2012 to 2016. Nínú ìwé ìròyìn ni a ti ṣa àwọn ìròyìn àti àkọsílẹ̀ láti ọwọ́ọ ilé ẹjọ́ Oníwàádìí-ẹni-tí-ó-kú. Ní ìsàlẹ̀ ni àwòrán-eré ránpẹ́ ìrìnàjò afẹ́ ọdún-un 2017 ní oríi YouTube Ó súnmọ́, síbẹ̀ ó jìnà Iye ènìyàn tí ó ń gbé ní ilẹ̀-tí-omí-fẹ́rẹ̀ẹ́-yíká Kowloon tó bíi èèyàn 40,000 ní orí ìwọ̀n kìlómítà kọ̀ọ̀kan, àti bí i ènìyàn 20,000 ni ó ń gbé Yau Ma Tei. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ńláǹlà ni a pín sí kéékèèké. Àwọn ènìyàn ń gbé súnmọ́ ara wọn, àmọ́ síbẹ̀, wọ́n jìnà sí ara wọn. Àìmọye àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìrìnàjò afẹ́ náà jẹ́ àgbàlagbà. Bàbá arúgbó kan pa ara rẹ̀ nígbà tí ó bẹ́ láti ojúu fèrèsé ilé alájà-mẹ́rin pẹ̀lú okùn tí ó so mọ́ ọrùn. Òkúu rẹ̀ ń fì ní ìta ògiri ilé náà ní títì ní àárín alẹ́, àmọ́ kò sí ẹni tí ó se àkíyèsí àfi ní ìgbà tí ó di fẹ̀ẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn alùgbé ilé òdì kejì ṣí fèrèsée wọn. Òmíràn ní í ṣe pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà méjì tí a bá òkúu wọn nínú ilé, ọ̀kan kú ikú ebi. Àsẹ̀yìnwá ni ó tó yé wípé ọkọ náà ni ó ṣe olùtọ́jú aya, ẹni tí ó arán ń ṣe. Ọkọ náà kọsẹ̀ nínú yàrá ìgbàlejò, ó sì kú, ebí sì ṣe wẹ́rẹ́ pa ìyàwó sí orí ibùsùn. Ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ wípé kò sí ẹni tí ó fura sí irú ìgbé ayé ìjìyà àwọn àgbàlagbà méjì. Gẹ́gẹ́ bí ètò ìkànìyàn ọdún-un 2016, mílíọ̀nù èèyàn 1.16 million ni ọmọ ọdún 65 àti jù bẹ́ẹ̀ lọ ní Hong Kong ìyẹn 15.9 ìdá gbogbo ènìyàn. Ẹgbẹ̀rún 150 àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni ó ń dá gbé. HK$5,780 (US$720) ni owó oṣù àwọn àgbàlagbà tí í ṣe òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì ní ọdún-un 2016 àti owó ìrànwọ́ ìjọba lápapọ̀. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, owó oṣù tí ó kéré jù lọ nínú tó HK$16,800 (US$2,200) dollars. Àmọ́ gbígbé pẹ̀lú ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ kò kan ti ìtìlẹyìn. Ìjàmbá oríṣi ni ó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹbí ní ìlú, pàápàá jù lọ ní àárín àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé, ọmọdébìnrin ọmọ ọdún 15 ni olóògbé tí ó máa ń múra bí ẹ̀dá-inú ìtàn tí a mọ̀ sí cosplay. Ó f'akọyọ nínú ẹ̀kọ́ọ rẹ̀ àmọ́ ó bá ẹbíi rẹ̀ ní gbólóhùn asọ̀ nítorí olólùfẹ́ẹ rẹ̀. Àbálọ àbábọ̀, ó kúrò ní ilé-ìwé, ó sì di ẹni-àpẹẹrẹ àwòrán láti so ẹ̀mí àti ara ró. Ẹni tí ó ṣiṣẹ́ fún tí ó san owó ọ̀yà HK$500 dollars (US$65) fún un ni ó pa a. Òmíràn jẹ́ òkú ọmọ-ọwọ́ kan tí ìwọ́ọ rẹ̀ ṣì wà ní a ara rẹ̀, tí obìrin kan tí ó ń ṣe ìmọ́tótó ìbùdókọ̀ abẹ́-ilẹ̀ ní Yau Ma Tei bá nínú àpò kan. Lẹ́yìn ìwádìí, àwọn ọlọ́pàá ṣe àrídájú wípé ọmọ-ọ̀dọ̀ kan láti ilẹ̀ òkèèrè tí ó ń bẹ̀rù wípé ọ̀gá òun yóò lé òun ni ẹnu iṣẹ́ bí ó bá mọ̀ wípé òun ní oyún ni ìyáa rẹ̀. Obìrin náà jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ọ rẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n. Ní abala ìrìnàjò afẹ́ yìí, amọ̀nà ṣe ìbéèrè: ṣé àwọn ọ̀gá obìnrin náà kò jẹ̀bi bí? Kò sí bí ó ṣe lè ṣẹlẹ̀ kí wọn ó máà mọ̀ wípé ẹni tí ó ń ṣiṣẹ́ fún wọn ní ojúmọ́ ní oyún ní inú. Ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó wà ní Hong Kong ju 370,000 lọ, òfin ṣì fi àyè gbà wọ́n kí ó máa gbé nínú ilé ọ̀gáa wọn. Èyí ni àyè fi sílẹ̀ láti lè rí wọn bá sùn bí wọn bá ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí púpọ̀, láì jẹun tí ó ṣe ara ní oore, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn ọdún kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn wáyé, ọmọ-ọ̀dọ̀ ilẹ̀-òkèèrè mìíràn gba ìdádúró ní ẹnu iṣẹ́ fún oyún tí ó ní. Ó gba obìnrin náà ní ọdún méjì gbáko nílé ẹjọ́ láti jà fún ìdádúró láì bá òfin mu ní ẹnu iṣẹ́. Ìpànìyàn ní àárín àwọn ènìyàn Ọ̀gọ̀rọ̀ ìpànìyàn ní Yau Ma Tei jẹ́ ẹsẹ̀ tí ó ti ọwọ́ àwọn ènìyàn fún ra wọn wá, tí ó jẹ́ ẹsẹ̀ tí wọn kò gbèrò tàbí pa ète rẹ̀ tẹ́lẹ̀, tí àwọn tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ sì ṣe àṣìṣe. Ó ní ìṣẹ̀lẹ̀ tí ọkùnrin kan pa ẹ̀gbọ́n-ọn rẹ̀ ọkùnrin ní ìta gbangba ní ojúu títì pẹ̀lú ọbẹ̀ ìwọ̀n ínṣì mẹ́sàn-án tí ó wọ inú ẹ̀dọ̀ fóró ẹ̀gbọ́n-ọn rẹ̀ lọ. Ẹ̀bùn ni ó yẹ kí ọbẹ̀ náà jẹ́ fún ẹ̀gbọ́n náà. Apànìyàn kan takú sí ibi ìpànìyàn lẹ́yìn tí ó pa ènìyàn tán; òmíràn fi ìwé pẹlẹbẹ ìdánimọ̀ọ rẹ̀ gba iyàrá tí ó tọ́jú òkú ẹni tí ó pa sí. Ìpànìyàn mìíràn wáyé ní ilé ìtaja-ohun-èlò-inú-ilé. Ẹ̀rọ-ayàwòrán amóhùnmáwòrán ká ìṣẹ̀lẹ̀ náà sílẹ̀. Onírìn àjò ìgbafẹ́ tí ó ń lo ìwé-ìrìnnà Orílẹ̀-èdè Canada ni apànìyàn náà, ẹni tí ó gún òǹtajà ìsọ̀ náà nígbà tí òǹtajà bíi léèrè ìdí tí ó fi kó ọjà láì san owó. Àlábàápàdé àwọn ẹ̀mí àti òjìjíi wọn Ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Àwọn kan kópa nítorí wọ́n fẹ́ rí àrídájú; àwọn mìíràn rí i bí ọ̀nà láti fi ìmọ̀ kún ìmọ̀. Oníṣègùn kan tí í ṣe ikọ̀ òṣìṣẹ́ ìlera tí ó ṣe ìrìnàjò náà sọ wípé: Ẹni ọ̀ràn yìí dà bíi àwọn aláàárẹ̀ tí a máa ń bá pàdé nínú ìyára ìtọ́jú àwọn tí ó ní ìjàmbá àti ìtọ́júu pàjàwìrì – àwọn tí egbògi olóró tí sọ di ìdàkudà, àwọn tí ó ń sun títì, àwọn ogún-lé-mi-dé. Iṣẹ́ẹ gbogbo wa ni láti dóòlà ẹ̀míi wọn ní yàráa pàjàwìrì. Àmọ́ wọ́n máa ń kanra nígbà mìíràn. Kì í rọrùn bí a bá ń ṣe ìtọ́júu wọn, nítorí náà a máa sọ sùúrù nù. Ìrìnàjò afẹ́ yìí rán wa létí wípé a nílòo sùúrù bí a bá ń dá àwọn aláàárẹ̀ lóhùn. Àti pé ayé ìrora ni wọ́n ń gbé, wọ́n sì ń tiraka láti gbé. Onírúurú ikú ni yóò pa gbogbo àwọn olùgbée 20,000 Yau Ma Tei. Ìgbàgbọ́ọ wa ni wípé bí ikú bá kanlẹ̀kùn, ẹ̀míi wọn yóò máa ráre kiri ní àárín-in àdúgbò àti ní òpópónà, láti máa rán àwọn ènìyàn létí nípa ìtúmọ̀ ìwà láyé. Ìrìnàjò yìí ń lépa láti pèsè àyè fún àwọn òjìjí láti sọ ìtàn ara wọn. Ohun tí ó ń fa ikú ni ìbàjẹ́ ọkàn tí a ò wò sàn. Ìbàjẹ́ ọkàn ní ìwòsàn, a sì lè dènà ìpànìyàn. Ó lè rí ìrànwọ́ fún àwọn tí ó ń bá ìparaẹni fà á àti àwọn tí ó wà nínú ìbàjẹ́ ọkàn. Lọ sí Befrienders fún ojú òpó ìbánisọ̀rọ̀ ìdènà ìparaẹni ní orílẹ̀-èdèe rẹ. Spiny Babbler, ẹyẹ orílẹ̀-èdè Nepal, fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àti olólùfẹ́ ẹyẹ mọ́ra Spiny Babbler, ẹyẹ tí a kò le è rí níbòmìrán àyàfi ní Nepal. Àwòrán láti ọwọ́ọ Sagar Giri. A lò ó pẹ̀lú àṣẹ. Bí-ó-ti-lẹ-jẹ́-pé ẹ̀yà ẹyẹ orílẹ̀ èdè Nepal ju 800 lọ, ẹyẹ Spiny Babbler (Turdoides nipalensis) jẹ́ ẹ̀dá tí kò sí ní ibòmíràn àyàfi orílẹ̀ èdè náà. Ẹyẹ aláwọ̀ eérú-àti-pupa-rẹ́súrẹ́sú náà, tí à ń pè ní Kaande Bhyakur ní èdè ìbílẹ̀ Nepali, ń fi igbó ṣe ìtẹ́ a sì lè fi ojú bà á bí ó bá ń fò lókè lálá láti ìwọ̀n mítà 500 sí mítà 2135. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé Spiny Babbler náà ti fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àgbáyé mọ́ra fún ọdún pípẹ́, ìbàjẹ́ àyíká ti ń ṣe ìdẹ́rùbà àkàndá, ẹyẹ tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn yìí. Nepal ní ọ̀wọ̀ ẹyẹ oríṣi 876, tí ọ̀kan ṣoṣo nínúu wọn sì jẹ́ irú èyí tí kò sí ní ibòmíràn lórí ilẹ̀ ayé (Spiny Babbler). Ẹyẹ náà tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi jẹ́ alárédè nínú ìṣẹ̀dáa rẹ̀ kò sì rọrùn láti rí, bíkòṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àkókò ìtọ́jú ọmọ bíbí tí àwọn akọ máa ń kọrin kiri agbègbè. Orin ẹyẹ Spiny babbler (Turdoides nipalensis), ẹyẹ tí a kò le è rí níbòmìrán àyàfi ní Nepal tí a ti mọ̀ lọ́jọ́ tí ó pẹ́ Ó máa ń wá kòkòrò nínú koríko ilẹ̀, ẹ̀kànànkan ni a sì máa ń rí i. Spiny Babbler máa ń bà lé ẹ̀ka koríko àti igi kéékèèké láti kọrin, àgógó ẹnu ẹyẹ yóò wà ní òkè irú ní ìsàlẹ̀. Ó dára ní wíwò, iké oríṣiríṣi. Orin rẹ̀ ni a fi ń mọ ibi tí ó wà, àárín oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ àti Ọ̀wàrà. Ẹ̀dá ẹyẹ yìí máa ń fò sókè lálá nínú àwọn àkókò kan nínú ọdún. Ẹyẹ Spiny Babbler, tí a lè rí ní Nepal nìkan, ti fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àti olólùfẹ́ ẹyẹ káríayé mọ́ra. Don Messerschmidt kọ nípa àkọsílẹ̀ tí onímọ̀-nípa-ẹyẹ S. Dillon Ripley ṣe nípa ẹyẹ náà nínú ìwée rẹ̀ Ìṣàwárí ẹyẹ Spiny Babbler Ó jẹ́ ọ̀wọ̀ ẹyẹ tí kò ka àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì sí fún ọdún gbọgbọrọ, láti ọdún 1843 tàbí 1844. Ní ìgbà yẹn àwọn aṣiṣẹ́ fún Brian Hodgson tí ó jẹ́ aṣèwádìí Nepali tí ṣe àkójọ onírúurú àpẹẹrẹ, ”ó kọ. Ẹyẹ Spiny Babbler “ti jẹ́ ẹranko tí ó ju ìmọ̀ ènìyàn lọ ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́, ọ̀kan nínú ọ̀wọ̀ ẹyẹ márùn-ún ní India, pẹ̀lú Àparò Òkè gíga, kò sí lórílẹ̀ ayé mọ́n. Ṣùgbọ́n bí èrò mi bá jẹ́ òtítọ́, ó ń fò kiri níbi ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Rekcha.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ikọ̀-ọba orílẹ̀-èdè America tẹ́lẹ̀ sí ìlú Nepal Scott DeLisi fi ọ̀pọ̀ ọdún wá ẹyẹ yìí àti láti ya àwòrán-an rẹ̀. Birder David Walsh túwíìtì Ẹgbẹ́ Onímọ̀-nípa-ẹyẹ ṣe ìrìnàjò láti Kathmandu sí Chitwan ní àná. Pabambarì ni ìfojúrí ẹyẹ tí kò sí ní ibòmíràn lórí ilẹ̀ ayé, Spiny Babbler. Ẹyẹ náà ti ń dínkù látàrí ìgbẹ́ pípa fún iṣẹ́ ọ̀gbìn àti ìtẹ́lọ ìgbèríko di ìgboro. Bí a bá yọ ti agbègbè ààbò kúrò, nígbà mìíràn pípa ẹyẹ yìí fún oúnjẹ, ní òkè kékeré tí ó yí àfonífojì Kathmandu ká ti mú kí ẹyẹ Spiny Babbler dínkù ni iye. Síbẹ̀, ohun tí ó ń fa àdánù ní agbègbè kan náà lè mú wọn pọ̀ ní agbègbè mìíràn. Bí igbó ṣe ń dínkù látàrí ìgbẹ́ pípa àti igi gẹdú gígé jákèjádò orílẹ̀ èdè náà, igbó tí wọ́n fi ṣe ilé ti di ti nǹkan mìíràn. Àmọ́ ṣá ìgbà àti àkókò ni yóò sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹyẹ ìlú Nepal tí kò sí ní ibòmíràn. Fún ìyọsọ́tọ̀ tí wọ́n yọ òun nìkan láti yẹ ara rẹ̀ wò ní ilé ìtajà ìgbàlódé kan ní Serbia, gbajúgbajà ìràwọ̀ òṣèré orí-ìtàgé Roma fi ẹ̀sùn ìwà elẹ́yàmẹyà kan ilé ìtajà náà Ìràwọ̀ òṣèré orí-ìtàgé ìlú Serbia Nataša Tasić Knežević, àwòrán láti ọwọ́ọ Dzenet Koko, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ. Àwọn gbàgede ìtàkùrọ̀sọ ẹ̀rọ-alátagbà ìlú Serbia gbaná lẹ́yìn tí olórin àti òṣèré ìbílẹ̀ Nataša Tasić Knežević, tí ó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Roma fi ẹ̀sùn kan ilé ìtajà-ìgbàlóde kan tí ó wà ní ìgboro Novi Sad fún ìwà ìyàsọ́tọ̀ ẹ̀yà nínú ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ojú-ẹsẹ̀ kan lórí Facebook. Nínú fídíò náà, tí ó gbé-sórí-áfẹ́fẹ́ ní ọjọ́ 29, oṣù Ọ̀pẹ lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀, arábìnrin Tasić Knežević ṣàlàyé pé bí òun ṣe ń jáde síta nínú ilé ìtajà ńlá náà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn òǹrajà mìíràn ni ẹ̀rọ adènà àfọwọ́rá dún. Bí àwọn ènìyàn yòókù ṣe ń jáde síta, àwọn ẹ̀ṣọ́-aláàbò ilé ìtajà náà ní kí ó dúró tí wọ́n sì tẹ̀síwajú láti yẹ ara rẹ̀ wò ní gbangba tí àwọn òǹwòran bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́. Ìwé orin, ìwé àti àpò-àpawómọ́-ìléwọ́ ni wọ́n rí nínú àpò-àgbékọ́yìn-in rẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Ṣẹẹrẹ ọdún 2019, fídíò náà dédé pòórá pẹ̀lú àlàyé ránpẹ́ nípa arábìnrin Knežević. Bíótilẹ̀jẹ́pé kòì tíì wá sí gbangba kí ó ṣàlàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀, àwọn ẹlòmíràn ń sọ pé fúnra rẹ̀ ni ó yọ ọ́ kí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ lè tán bọ̀rọ̀. Láàárín ọjọ́ díẹ̀, àwọn ènìyàn tí ó tó bíi ẹgbẹ̀rún 60 ti wo fídíò rẹ̀, tí wọ́n sì pín in lọ́nà 350, tí ó sì gba èsì tí ó tó 700. Ilé iṣẹ́ Ìkóròyìnjọ Orí-ayélujára Olómìnira Bulka ni ó kọ́kọ́ ro ìyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣáájú àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn Bulka mìíràn. Akọrin-olóhùn-òkè ni arábìnrin Tasić Knežević ní Gbọ̀ngan Eré-ìtàgé ti orílẹ̀-èdè Serbia tí ó wà ní Novi Sad, ìlú kejì tí ó tóbi jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà. Tẹ́lẹ̀ rí, ó ṣiṣẹ́ ní Belgrade Atelje 212. Ó tún jẹ́ akọrin-ṣeré àti àdánìkànkọrin tí ó gbajúmọ̀, ó sì máa ń kọ orin àdánìkànkọ nípa àṣà Roma tí ó jẹ́ orírun rẹ̀. Nínú fídíò náà, arábìnrin Knežević sọ pé alábòójútó ilé ìtajà náà bẹ̀bẹ̀ lẹ́yìn tí òun ṣe àròyé nípa ìwọ̀sí náà, ṣùgbọ́n pé inú òun kò dùn sí bí àwọn èrò tí ó pé jọ lé òun lórí ṣe yẹ̀yẹ́ òun. Ó ní ọkùnrin àgbàlagbà kan pariwo pé kí wọ́n “kó pàǹtí yẹn jáde”, ìyẹn túmọ̀ sí wípé kí àwọn òṣìṣẹ́ ó ju òun jáde síta nínú ilé ìtajà náà nítorí pé òun jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Rome. “Ta ni ó ń kọrin níbẹ̀ yẹn” jẹ́ eré Yugoslavia ayé ìgbà 1980 tí ó sì di ipò ẹgbẹ́-ìmùlẹ̀ láàárín àwọn Balkan. Nínú ìtàn náà, wọ́n ṣèṣì fẹ̀sùn olè kan àwọn olórin Roma méjì, orí ni ó kó wọn yọ lọ́wọ́ ìjìyà láìsí ìdájọ́. Ilé-iṣẹ́ tí ó ni ilé ìtajà-ìgbàlóde Maxi, Delez Srbija, ṣe àgbéjáde àkọsílẹ̀ ìtúúbá lọ́jọ́ kan náà, ó sọ pé àwọn “gbàgbọ́ pé èyí á wà bí ìṣẹ̀lẹ̀ ìyàsọ́tọ̀ tí ó mú ìfura ẹni tí kò yẹ dání pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ò ní wáyé mọ́ lọ́jọ́ iwájú. Ilé-iṣẹ́ náà fi kún un pé àwọn á ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ wọn lórí bí a ṣe ń hùwà bí wọ́n bá fura sí olè jíjà. Ní ọjọ́ kejì, Miloš Nikolić tí ó jẹ́ adarí ọ́fíìsì tí ó ń ṣe àfikún Novi Sad mọ́ Roma sọ̀rọ̀ tako ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó ní; “gbogbo ìwádìí tí wọ́n ṣe fi hàn pé àwọn ará Roma lọ́kùnrin lóbìnrin ni ẹ̀yà tí a yà sọ́tọ̀ jù lọ ní orílẹ̀-èdèe wa. A ní láti ṣiṣẹ́ pọ̀ láti yí i padà!” Ní 31 oṣù Ọpẹ, Igbá-kejì Alákòóso Ìgbìmọ̀ Ìjọba àti Ààrẹ Àjọ-tí-ó-ń-fètò-sí Ìmúdọ́gba Akọ-àtabo ní àwùjọ, Zorana Mihajlović náà sọ̀rọ̀ tako àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtajà Maxi pé “ìwà ìbanilórúkọjẹ́ ni wọ́n hù àti pé wọ́n jẹ̀bi”. Kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí ó yẹ kí wọ́n ṣe sí ìyàsọ́tọ̀ àwọn ọmọ Roma ní Serbia… Bíótilẹ̀jẹ́pé ó dàbí ẹni pé arábìnrin Knežević ti yọ ara rẹ̀ kúrò lórí Facebook, bóyá láti lè jẹ́ kí ọ̀ràn náà ó silẹ̀, ó fi àlàyé-nípa-ara rẹ̀ orí Twitter sílẹ̀. Ní alẹ́ ọjọ́ tí ó ṣíwájú Ọdún Tuntun, ó fi àtẹ̀jáde ṣókí sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ẹ̀ mi ọ̀wọ́n, ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò dùn mọ́ni nínú kan ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn, ṣùgbọ́n mo nírètí pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ náà á pín pẹ̀lú ọdun 2018 àti pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ò ní wáyé mọ́. Ẹ jẹ́ kí a jẹ́ ènìyàn ẹlẹ́ran ara, ohun tí ó dára jù ní ayé yìí nìyẹn. Ilé-iṣẹ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Ìbílẹ̀ Fagilé Ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ pẹ̀lú àwọn ajìjàǹgbara LGBT lẹ́yìn ìhalẹ̀mọ́ sí olóòtú Ilé-iṣẹ́ Echo ti Moscow ní Yaroslavl tí ó jẹ́ ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Echo ti Moscow ìsopọ̀ tí ó ti dá dúró fún ìgbà pípẹ́ ní Russia fagi lé ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ pẹ̀lú àwọn ajìjàǹgbara LGBT lẹ́yìn tí wọ́n gba ìhalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó kórìíra-ìbálòpọ̀-láàárín-akọ-àti-akọ, olóòtú ilé-iṣẹ́ náà Lyudmila Shabuyeva sọ̀rọ̀ nínú àkọsílẹ̀ Facebook kan: Ní àná, a gba ìhàlẹ̀ kan tí ó ń lérí mọ́ àwa àti àwọn àlejòo wa tí a bá tẹ̀síwajú pẹ̀lú ètò ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ọ wa nípa LGBT. Mò ń fagi lé ètò náà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn tí ò sí ní abẹ́ ìṣàkóso ìjọba Novaya Gazeta ti ṣe sọ, ó yẹ kí ètò náà tí yóò ṣe àfihàn àwọn ajìjàǹgbara LGBT ní Yaroslavl wáyé ní òwúrọ̀ Ọjọ́rú 23, ní oṣù Ṣẹẹrẹ. Àwọn ajìjàǹgbara yìí kan náà ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ẹ̀hónú hàn ní gbàgede ìlú láti tako ìfìyàjẹ àwọn aṣe-ìbálòpọ̀-akọ-àti-akọ ní Russia, pàápàá jùlọ ní orílẹ̀ Chechnya. Ilé-iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà pè wọ́n láti fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò nípa ìfẹ̀hónúhàn àti ìrírí wọn fún jíjáde sí gbangba gẹ́gẹ́ bíi aṣe-ìbálòpọ̀-akọ-àti-akọ ní ẹ̀ka-ìlúu Russia. Ìkéde Shebuyeva àkọ́kọ́ nípa ètò náà fa ẹgbẹlẹmùkù èébú ìkórìíra-ìbálòpọ̀-láàárín-akọ́-àti-akọ nínú àwọn èsì, tí èsì sì wá láti ọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ọba kan bákan náà, ṣùgbọ́n ìyẹn ò mú ọkàn-an rẹ̀ kúrò, ó sọ fún Novaya Gazeta. Ṣùgbọ́n ní alẹ́ ọjọ́ tí ètò náà ku ọ̀la, Shabuyeva sọ̀rọ̀ pé òun gba ��pè àjèjì láti orí òpó ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ kan tí kò ṣe é dámọ̀, ẹni náà sì sọ fún òun pé bí òun bá tẹ̀síwajú pẹ̀lú ètò náà bí ó ṣe ti pinnu, wọ́n máa fi igi ìgbábọ́ọ̀lù-afọwọ́jù pàdé àwọn àlejò rẹ ní ìta ilé-iṣẹ́ náà. Òun náà sì lè kojúu wàhálà, onípè àjèjì náà léríléka. Nítorí ìbẹ̀rù fún ààbò àwọn àlejòo rẹ̀, Shabuyeva fagilé ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà tí ó sì fi ètò mìíràn rọ́pòo rẹ̀. Ìfẹ̀hónúhàn tí ó wáyé ní gbàgede ìlú wà lára ìkéde gbogboògbò saveLGBTinRussia tí wọ́n fi ń polongo ìyà tí ó rorò tí wọ́n fi ń jẹ àwọn ènìyàn aṣe-ìbálòpọ̀-akọ-àti-akọ ní orílẹ̀ Chechnya. Àwọn ìwọ́de àti ìfẹ̀hónúhàn irú èyí wáyé ní àwọn ìlú mìíràn ní Russia. Ìlú ń ké pe àwọn ọmọ rẹ̀ (àwọn ọmọ ìlú) láti dojú ìjà kọ ìwà elẹ́yàmẹyà àti ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní Russia òde-òní. Jẹ́ kí ìpèe rẹ̀ ta ọ́ jí! [àmì náà ń sọ pé: Ẹ̀KA ÌṢÈDÁJỌ́ TI ORÍLẸ̀-ÈDÈE RUSSIA Ò RÍ ÀWỌN AṢE-ÌBÁLÒPỌ̀-AKỌ-ÀTI-AKỌ NÍ CHECHYA. WỌ́N WÀ NÍBẸ̀: NÍNÚ ÀWỌN ỌGBÀ Ẹ̀WỌ̀N ÀTI IBOJÌ-ÒKÚ. Ẹ̀TANÚ ÌBÁLÒPỌ̀-LÁÀÁRÍN-AKỌ-ÀTI-AKỌ = ÌJỌBA AFIPÁMÚNI Nínú oṣù Igbe 2017, Novaya Gazeta jábọ̀ pé àwọn aláṣẹ ní Chechnya, ti ìlú oníjọba Ìmọ́lẹ̀ tí ó ń rí ìdààmú jù ní gúúsù Russia tí ajagun fẹ̀yìntì Ramzan Kadyrov, ń ṣe olóríi rẹ̀, ń ṣe ìpolongo tí ó rorò tí ó ń tako ìtẹ̀mọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn tí í ṣe LGBT tí ó ń gbé nínúu rẹ̀. Ìròyìn tí ó jáde ní àìpẹ́ sọ pé “ìfọ̀mọ́” náà le gidi gan-an ni, pẹ̀lú ikú èèyàn méjì ó kéré tán àti ogunlọ́gọ̀ àwọn tí ó wà ní àtìmọ́lé tí ó lòdì sí òfin. Wọ́n fagi lé ìfìwépè Adarí iléeṣẹ́ tó ń ṣètò Ìṣàjò-papọ̀-wa-ọkọ̀-kí-n-wa-ọkọ̀ sí iléeṣẹ́ tẹlifíṣàn Russia lẹ́yìn tí olóòtú ètò rí i pé obìnrin ni Àgékúrò àwòrán adarí iléeṣẹ́ náà, Irina Reyder ní ọ́fíìsì iléeṣẹ́ BlaBlaCar ti Russia. Àwòrán láti orí Ojú ewé. Irina Reyder tí ó jẹ́ adarí iléeṣẹ́ BlaBlaCar ní Russia ní wọ́n fagi lé ìfìwépè òun sí ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ kan pẹ̀lú iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán-an ti ìjọba, Channel One lẹ́yìn tí olóòtú náà rí i pé obìnrin ni òun. Reyder kọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà sójú ìwé Facebook rẹ̀. Ó ní òun gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ìpè olóòtú ètò náà pẹ̀lú aṣojú ilé iṣẹ́ BlaBlaCar fún ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwùjọ tí òun sì gba ohùn-un wọn sílẹ̀: (Olóòtú ètò “Ojúmọ́ Ire”): Báyìí ni a ṣe gbèrò láti ṣe é; akọ̀ròyìn-in wa á máa wa ọkọ̀ bí yóò ṣe máa fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ lẹ́nu alámọ̀dájúu yín. (Aṣojú iléeṣẹ́ BlaBlaCar fún ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwùjọ): Bẹ́ẹ̀ ni, Ìyẹn dára Ta ni yóò wá jẹ́ alámọ̀dájú náà? Adarí iléeṣẹ́ wa ni, Irina Reyder Ẹ̀n… Ẹ ti fìgbà kan ní ọkùnrin tó dára ní ipò náà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bẹ́ẹ̀ ni, a ti ní Alexey Lazorenko gẹ́gẹ́ bí Adarí, Irina Reyder ni nísẹ̀yín. Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa àyípadà tí ó wáyé nínú ìdarí iléeṣẹ́ yín lọ́dún tó kọjá. Ṣùgbọ́n Irina kò ní le è wúlò gẹ́gẹ́ bí alámọ̀dájú, ó nírú ẹni tí àwọn olùgbọ́ọ wa máa ń nífẹ̀ẹ́ sí. Fún àpẹẹrẹ, tí a bá ní agbẹjọ́rò gidi kan. Ó ń láti jẹ́ ọkùnrin. Tàbí ẹni tí ó mọ̀ nípa ọkọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ – ọkùnrin ni, kó má jẹ̀ ẹ́ obìnrin. Bóyá kí ìwọ Sergey ó ṣe ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ náà? Lẹ́yìn tí aṣojú iléeṣẹ́ náà fún ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwùjọ, Sergey sọ fún olóòtú ètò náà pé kò sí alámọ̀dájú ọkùnrin kankan ní iléeṣẹ́ naa, ó ní olóòtú ètò náà ṣe ìlérí láti padà wá lẹ́yìn tí ó bá ti bá olóòtú àgbà ètòo wọn sọ ọ́. Nínú ìpè kan lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n sọ fún aṣojú iléeṣẹ́ BlaBlaCar pé ètò náà ti yí padà, pé àwọn á máa ṣe ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ pẹ̀lú àwọn oníbàáràa wọn dípò wọn. “Kí lẹ rò? Ṣé àwọn alámọ̀dájú tuntun yìí á mọ̀ dájú dánu? Reyder ń béèrè ìbéèrè ìkẹ́gàn náà lọ́wọ́ àwọn èèyàn-an rẹ̀. Nínú èsì kan sí TJournal, tí ó jẹ́ iléeṣẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ àti ìròyìn ẹ̀rọ alátagbà àti orí ayélujára. Ẹ̀ka ìròyìn Channel One ò fi òtítọ́ ìtàkùrọ̀sọ yìí pamọ́, ṣùgbọ́n wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé ọ̀rọ̀ náà kò ṣègbè lẹ́yìn akọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlàyé wọn kò fìdí èyí múlẹ̀ tó: Akọ̀ròyìn méjì, ọkùnrin àti obìnrin kan ń gbèrò láti ṣàfihàn ìyàtọ̀ tí ó wà nínúu bí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ń hùwà sí ìfowópamọ́. Akọ̀ròyìn lóbìnrin á ní láti fọ̀rọ̀wọ́rọ̀ pẹ̀lú alámọ̀dájú ọkùnrin kan nígbà tí Akọ̀ròyìn lọ́kùnrin á ní ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin. Nítorí pé èròńgbà Akọ̀ròyìn obìnrin yẹn ni láti wo bí wọ́n ṣe ń tọ́jú owó bí wọ́n bá gbé ọkọ̀, a nílò láti bá aṣojú iléeṣẹ́ tó ń ṣètò ìrìnnà-papọ̀-wa-ọkọ̀-kí-n-wa-ọkọ̀ kan sọ̀rọ̀ (bẹ́ẹ̀ ni, nítorí àlàkalẹ̀ ètò náà ni, kì í ṣe nítorí àìfẹ́dọ̀ọ́gba akọ àtabo, ó ní láti jẹ́ ọkùnrin). Channel One ò sọ bí ìyàtọ̀ ṣe wà láàárín bí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ń ronú sí ìfowópamọ́. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ tako ìhùwàsí iléeṣẹ́ tẹlifíṣàn yìí. Adarí iléeṣẹ́ BlaBlaCar, Irina Reyder sọ pé wọ́n fagi lé ìfìwépè òun wá sórí ètò Ojúmọ́ Ire lórí Channel One lẹ́yìn tí olóòtú rí i pé obìnrin ni òún jẹ́. Ó yani lẹ́nu pé àwọn ohun kan ṣì wà nínú ìyírí àwọn Channel One tí a kò mọ̀. Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ burúkú tí Channel One gbọ́ lórí ayélujára, Russia sì ní iṣẹ́ ńlá láti ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìbádọ́gbà akọ àti abo. Russia wà ní ipò 75 nínú àwọn orílẹ̀-èdè 149 tí Àjọ tó-ń-ṣètò-ọrọ̀-Ajé Lágbàáyé ṣàyẹ̀wò fún lọ́dún 2018 nínú Ìjábọ̀ Àlàfo tó wà láàárín Akọ àti Abo Lágbàáyé, ó ń ṣe dáadáa ní ti ìbádọ́gbà nínú rírí ètò ìlera àti ètò ẹ̀kọ́ lò fún àwọn obìnrin, ṣùgbọ́n wọ́n ń fà sẹ́yìn nínú ètò ìṣòfin láti jà fún ẹ̀tọ́ọ wọn. Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ abo ní Russia máa ń sábàá lo gbàgede ẹ̀rọ alátagbà àti ẹ̀fẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ sí ìhùwàsí àti ìṣe àwọn tí ó ń ṣègbè lẹ́yìn ẹ̀yà ènìyàn kan. 100 ọjọ́ fún Alaa: Ẹbí ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọ Íjípìtì ń ka ọjọ́ fún ìdásílẹ̀ẹ rẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n Lẹ́yìn tí ó ti lo ọdún 5 nínú ẹ̀wọ̀n, akọbúlọ́ọ̀gù ọmọ Íjípìtì àti ajàfúnẹ̀tọ́ Alaa Abd El Fattah yóò gba ìdásílẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n ní ọjọ́ 7, oṣù Ẹrẹ́nà, ọdún 2019. Ní ọjọ́ 8 oṣù Ọ̀pẹ, ẹbíi rẹ̀ ti ṣe àgbékalẹ̀ ìpolongo –“100 ọjọ́ fún Alaa” kí àtìmọ́lée rẹ̀ ó ba wá s'ópin ní mọnawáà. Ìdásílẹ̀ẹ rẹ̀ nínú oṣù Ẹrẹ́nà kì í ṣe ìsààmì òpin ìgbà Alaa ní ẹ̀wọ̀n, ṣùgbọ́n ìṣíkúrò sí ipò tí ó jẹ́ àṣekágbá àtìmọ́lée rẹ̀. Lẹ́yìn ìdásílẹ̀ẹ rẹ̀, Alaa yóò máa wá sun oorun alẹ́ ní àgọ́ ọlọ́pàá ìbílẹ̀ẹ rẹ̀ fún àfikún ọdún márùn-ún gbáko. Abẹ́ ìṣọ́ ọlọ́pàá ni yóò wà fún àkókò yìí. A fi ọwọ́ọ ṣìgún òfin mú Alaa a sì mú u kúrò ní ilé ẹbíi rẹ̀ nínú oṣù Belu ọdún 2013. Ọdún kan kọjá, nínú oṣù Èrèlé ọdún 2015, a gbé e re ilé ẹjọ́ a sì rán an ní ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún fún “àgbékalẹ̀” ìyíde kiri ìfẹ̀hànnúhàn lábẹ́ òfin ìyíde kiri ìfẹ̀hànnúhàn ọdún 2013 tí kò fi àyè gba ìyíde láìgbàṣẹ. Ní tòótọ́ ni ó kópa nínú ìyíde kiri tí ó ń tako ẹjọ́ tí àwọn ológun dá mẹ́kúnnú ní ọjọ́ 26 oṣù Belu ọdún 2013, Alaa kò kó ipa nínú àgbékalẹ̀ẹ rẹ̀. Ilé ẹjọ́ Cassation ti Íjípìtì fi ẹsẹ ẹ̀wọ̀n-ọn rẹ̀ múlẹ̀ nínú oṣù Belu ọdún 2017. Omar Robert Hamilton, olùkùu Alaa, to àwọn ète ìpolongo náà lẹ́sẹẹsẹ lóríi Twitter: Láti mú kí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ àti ọmọ àgbáyé ó fi ọkàn sí ìdájọ́ àti fún ìdásílẹ̀ẹ Alaa ní ọjọ́ 17 oṣù Ẹrẹ́nà. Láti gbé ìrò (‘ìṣọ́nikiri’ tàbí ‘ìdásílẹ̀-lẹ́wọ̀n-kọ́jọ́-ìdásílẹ̀-tó-pé’) sínú làákàyè àwọn ènìyàn gbogbo. Lẹ́yìn ìdásílẹ̀, Alaa ṣì tún ní láti sun ọrùn alẹ́ nínú àgọ́ ọlọ́pàá ìbílẹ̀ẹ rẹ̀ fún “ọdún márùn-ún”. A ní láti ṣe iṣẹ́ ìpìlẹ̀ fún ìtako èyí. Gbogbo olórí orílẹ̀-èdè Íjípìtì ni ó ti ṣe ìwádìí tàbí rán Alaa ní ẹ̀wọ̀n ní ojú ayée rẹ̀. Ní ọdún 2006, a fi ọwọ́ọ ṣìgún òfin mú u fún ipa tí ó kó nínú ìyíde kiri ìfẹ̀hànnúhàn tí kò fa ìdíwọ́ fún ẹnikẹ́ni. Ní ọdún 2011, ó lo oṣù méjì ní ẹ̀wọ̀n, àkókò yìí ni ìyàwóo rẹ̀ bí àkọ́bíi rẹ̀, Khaled. Ní ọdún 2013, a mú u a sì fi sínú àhámọ́ fún ọjọ́ 115 láì ṣe ìgbẹ́jọ́. Ó ti pẹ́ tí Alaa ti ń ṣiṣẹ́ lóríi ìjìnlẹ̀ ìmọ̀-ẹ̀rọ àti òṣèlú pẹ̀lú ìyàwóo rẹ̀, Manal Hassan. Ìdílé gbajúgbajà ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ni ó ti wà, adájọ́ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn Ahmed Seif El Islam, ni bàbáa Alaa, ẹni tí a ti rán lọ ní ẹ̀wọ̀n láì mọye ìgbà ní abẹ́ àṣẹ Hosni Mubarak. Ẹ̀gbọ́n-bìrin méjèèjì Abd El Fattah, Mona àti Sanaa Seif, jẹ́ agbèjà ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn bákan náà tí wọ́n sì ti ṣe ìpolongo alátakò ìjìyà mẹ́kúnnú lọ́wọ́ọ àwọn ológun ní ìlú náà. Ní ọdún 2016, Sanaa lo oṣù mẹ́fà ní ẹ̀wọ̀n nítorí wípé ó sọ̀rọ̀ àfojúdi sí alaṣẹ ìjọba. Àdánwòo Alaa jọ ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Íjípìtì tí ó wà ní ẹ̀yin gádà nítorí akitiyan wọn nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn. Ẹgbẹ́ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn sọ wípé, àwọn tí ìjọba rán ní ẹ̀wọ̀n ní Íjípìtì á tó 60,000. Gbogbo ẹni tí ìjọba bá fi ọwọ́ọ ṣìgún òfin mú ní Íjípìtì ní í jẹ ìyà oró, ìfarasin, àtìmọ́lé ọjọ́ pípẹ́ àti àdánìkangbé inúu túbú. Dídarapọ̀ mọ́n ìpolongo Ní inú ìwé tí a kọ sí àwọn àlejò tí ó wá sí RightsCon, àpérò tó dá lórí ẹ̀tọ́ irinṣẹ́ ẹ̀rọ-ayárabíaṣá tí ó wáyé ní Toronto nínú oṣù Èbìbì ọdún 2018, Alaa rọ àwọn alátìlẹ́yìn láti “ṣe àtúnṣe sí ìjọba àwa-arawa ti wọn”. Èyí ti fi ìgbà pípẹ́ jẹ́ ìdáhùn mi sí ìbéèrè náà “báwo ni a ṣe lè ṣe ìrànwọ́?” Mo ṣì ní ìgbàgbọ́ wípé [àtúnṣe ìjọba àwa-arawa] ni ìdáhùn kan ṣoṣo. Kì í ṣe ibi tí ò ń gbé nìkan, ṣiṣẹ́, san owó orí àti ṣe àkóso ibi tí ó ti ní ipa, àmọ́ ìfàsẹ́yìn fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn nínú ibi tí ìjọba àwa-arawa ti fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀ lè di lílò fún ìrúfin ẹ̀tọ́ ní àwọn agbègbè tí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn kò fi bẹ́ẹ̀ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀. Mo mọ̀ wípé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní òde òní jẹ́ ẹ̀rí wípé àtúnṣe pọ̀ láti ṣe. Mo ń retí ìmísí ọ̀nà tí ẹ ó gbà tún un ṣe. Kí ẹni tí ó bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ ìpolongo “100 ọjọ́ fún Alaa” ó fi “àròkọ, àwòrán tàbí ìṣe ìlọ́wọ́sí ìpolongo” ṣọwọ́ tí a lè tún tẹ̀ jáde sórí ibùdó-ìtàkùn-àgbáyé ìpolongo náà: Ìpolongo orísun-ọ̀fẹ́ – a óò máa tẹ àwọn ọgbọ́n àtinúdá tuntun síta, àmọ́ a nílò láti gba èrò tuntun àti agbára tuntun wọlé bákan náà. Torí ìdí èyí máa bá wa ronú! Bí ìgbà gbogbo, àmì ìpolongo ni FreeAlaa – jọ̀wọ́ darapọ̀ mọ́ wa fún ìpalẹ̀mọ́ ìdásílẹ̀ẹ Alaa. \ No newline at end of file