diff --git "a/yorubaCorpus/Ycorpusss_8.txt" "b/yorubaCorpus/Ycorpusss_8.txt" new file mode 100644--- /dev/null +++ "b/yorubaCorpus/Ycorpusss_8.txt" @@ -0,0 +1,7751 @@ +“Sibẹsibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Kí ló dé tí ọmọ kò fi ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀?’ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ bá ti ṣe ohun tí ó bá òfin mu, tí ó sì ti mú gbogbo ìlànà mi ṣẹ; dájúdájú yóo yè ni. +“Kí ni ẹ rí tí ẹ fi ń pa irú òwe yìí nípa ilẹ̀ Israẹli, tí ẹ̀ ń sọ pé,‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà tí ó kan,ni eyín fi kan àwọn ọmọ?’ +Ẹni tí ó bá ṣẹ̀ ni yóo kú: ọmọ kò ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀; baba kò sì ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ rẹ̀. Olódodo yóo jèrè òdodo rẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan burúkú yóo jèrè ìwà burúkú rẹ̀. +“Ṣugbọn bí eniyan burúkú bá yipada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń dá, tí ó ń pa òfin mi mọ́, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu, dájúdájú yóo yè ni, kò ní kú. +A kò ní ranti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóo yè nítorí òdodo rẹ̀.” +OLUWA ní: “A máa ṣe pé mo ní inú dídùn sí ikú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni? Ṣebí ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò lọ́nà burúkú rẹ̀, kí ó sì yè. +“Ṣugbọn bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀, tí ó ń ṣe àwọn ohun ìríra tí àwọn eniyan burúkú ń ṣe; ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ leè yè? Rárá! A kò ní ranti gbogbo òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe mọ́, yóo kú nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ ati ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. +“Sibẹsibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli: ọ̀nà tèmi ni kò tọ́ ni, àbí ọ̀nà tiyín? +Bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá. +Bí eniyan burúkú bá sì yipada kúrò ninu ìwà ibi rẹ̀, tí ó sì ń ṣe rere, yóo gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. +Nítorí pé ó ronú, ó sì yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ń dá, dájúdájú yóo yè, kò ní kú. +Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli ń wí pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ọ̀nà mi ni kò tọ́, àbí tiyín? +“Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní pa òwe yìí mọ́ ní ilẹ̀ Israẹli. +“Nítorí náà, n óo da yín lẹ́jọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ìwà olukuluku ni n óo fi dá a lẹ́jọ́. Ẹ ronupiwada, kí ẹ sì yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀ṣẹ̀ má baà pa yín run. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Ẹ kọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín tí ẹ̀ ń dá sí mi sílẹ̀. Ẹ wá ọkàn tuntun ati ẹ̀mí tuntun fún ara yín. Kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli? +N kò ní inú dídùn sí ikú ẹnikẹ́ni, nítorí náà, ẹ yipada kí ẹ lè yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Èmi ni mo ni ẹ̀mí gbogbo eniyan, tèmi ni ẹ̀mí baba ati ẹ̀mí ọmọ; ẹni yòówù tó bá dẹ́ṣẹ̀ ni yóo kú. +“Bí ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olódodo, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu; +bí kò bá bá wọn jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tabi kí ó bọ àwọn oriṣa ilé Israẹli; tí kò bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, tabi kí ó bá obinrin lòpọ̀ ní àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́; +tí kò ni ẹnikẹ́ni lára, ṣugbọn tí ó dá ohun tí onígbèsè fi ṣe ìdúró pada fún un; tí kò fi ipá jalè, tí ó ń fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì ń da aṣọ bo ẹni tí ó wà ní ìhòòhò, +tí kò gba owó èlé lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, tí ó yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ń dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ láàrin ẹni meji, +tí ó ń rìn ninu ìlànà mi, tí ó sì ń fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, olódodo ni irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo sì yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Iṣẹ́ Ẹnìkọ̀ọ̀kan. +OLUWA ní kí n sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn olórí Israẹli, +Ìyá rẹ dàbí àjàrà inú ọgbàtí a gbìn sí ẹ̀gbẹ́ odò;ó rúwé, ó yọ ẹ̀ka,nítorí ó rí omi lọpọlọpọ. +Ẹ̀ka rẹ̀ tí ó lágbárani a fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún àwọn olórí.Ó dàgbà, ó ga fíofío, láàrin àwọn igi igbó.Ó rí i bí ó ti ga, tí ẹ̀ka rẹ̀ sì pọ̀. +Ṣugbọn a fa àjàrà náà tu pẹlu ibinu,a sì jù ú sílẹ̀.Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn mú kí ó gbẹ,gbogbo èso rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.Igi rẹ̀ tí ó lágbára gbẹ, iná sì jó o. +Nisinsinyii, a ti tún un gbìn sinu aṣálẹ̀,ninu ilẹ̀ gbígbẹ níbi tí kò sí omi. +Iná ṣẹ́ lára igi rẹ̀,ó sì jó gbogbo ẹ̀ka ati èso rẹ̀.Kò sì ní igi tí ó lágbára mọ́,tí a lè fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ọba.Dájúdájú ọ̀rọ̀ arò ni ọ̀rọ̀ yìí, ó sì ti di orin arò. +kí n sọ pé:Abo kinniun pataki ni ìyá rẹ láàrin àwọn kinniun!Ó dùbúlẹ̀ láàrin àwọn ọ̀dọ́ kinniun,ó ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀. +Ó tọ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà;ó di ọ̀dọ́ kinniun.Ó kọ́ ọ bí wọ́n tí ń ṣe ọdẹ,ó sì ń pa eniyan jẹ. +Àwọn eniyan ayé gbọ́ nípa rẹ̀,wọ́n tàn án sinu kòtò wọn.Wọ́n fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú,wọ́n sì fà á lọ sí ilẹ̀ Ijipti. +Nígbà tí abo kinniun náà rí i pé ọwọ́ tẹ ọmọ òun,ati pé igbẹkẹle òun ti dòfo,ó mú òmíràn ninu àwọn ọmọ rẹ̀,ó tọ́ ọ di ọ̀dọ́ kinniun. +Ó ń yan kiri láàrin àwọn kinniun;nítorí ó ti di ọ̀dọ́ kinniun tí ó lágbára,ó kọ́ bí wọn tí ń ṣe ọdẹ,ó sì ń pa eniyan jẹ. +Ó wó ilé ìṣọ́ wọn lulẹ̀;ó sọ ìlú wọn di ahoro.Ẹ̀rù ba gbogbo Ilẹ̀ náà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀,nígbà tí wọ́n gbọ́ bíbú rẹ̀. +Àwọn orílẹ̀-èdè bá dójú lé e,wọ́n dẹ tàkúté fún un ní gbogbo ọ̀nà,wọ́n da àwọ̀n wọn bò ó,wọ́n sì mú un ninu kòtò tí wọn gbẹ́ fún un. +Wọ́n sọ ìwọ̀ sí i nímú,wọ́n gbé e jù sinu àhámọ́,wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni.Wọ́n fi sí àtìmọ́lé,kí wọ́n má baà gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Israẹli. +Orin Arò. +Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, dìde dúró, mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.” +Ó tẹ́ ìwé náà siwaju mi; mo sì rí i pé wọ́n kọ nǹkan sí i ní àtojú àtẹ̀yìn. Ọ̀rọ̀ ẹkún, ati ọ̀rọ̀ ọ̀fọ̀, ati ègún ni wọ́n kọ sinu rẹ̀. +Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀, ẹ̀mí OLUWA wọ inú mi, ó gbé mi nàró, mo sì gbọ́ bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀. +Ó ní, “Ọmọ eniyan, mo rán ọ sí àwọn ọmọ Israẹli, orílẹ̀-èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀, àwọn tí wọ́n ń ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Àwọn ati àwọn baba ńlá wọn ṣì tún ń bá mi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí. +Aláfojúdi ati olóríkunkun ẹ̀dá ni wọ́n. Mò ń rán ọ sí wọn kí o lè sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun wí fún wọn. +Bí wọn bá fẹ́ kí wọn gbọ́, bí wọn sì fẹ́, kí wọn má gbọ́. (Nítorí pé ọlọ̀tẹ̀ kúkú ni wọ́n), ṣugbọn wọn yóo mọ̀ pé Wolii kan ti wà láàrin wọn. +“Ṣugbọn ìwọ ọmọ eniyan, má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà ọ́, má sì bẹ̀rù ọ̀rọ̀ tí wọn ń sọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀gún ọ̀gàn ati ẹ̀wọ̀n agogo yí ọ ká, tí o sì jókòó láàrin àwọn àkeekèé, má ṣe bẹ̀rù ohunkohun tí wọn bá wí. Má jẹ́ kí ojú wọn dẹ́rù bà ọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. +O óo sọ ohun tí mo bá wí fún wọn, wọn ìbáà gbọ́, wọn ìbáà má gbọ́; nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ kúkú ni wọ́n. +“Ṣugbọn ìwọ, ọmọ eniyan, fetí sí ohun tí mò ń sọ fún ọ. Má dìtẹ̀ bí àwọn ọmọ ìdílé ọlọ̀tẹ̀ wọnyi. La ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí n óo fún ọ.” +Nígbà tí mo wò, mo rí ọwọ́ tí ẹnìkan nà sí mi, ìwé kan tí a ká sì wà ninu rẹ̀. +Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ọdún keje tí a ti wà ní ìgbèkùn, àwọn àgbààgbà Israẹli kan wá láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n sì jókòó níwájú mi. +“Nítorí náà, mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, wá sinu aṣálẹ̀. +Mo fún wọn ní òfin mi, mo sì fi ìlànà mi hàn wọ́n, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè. +Lẹ́yìn náà, mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi, kí ó máa jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi OLUWA yà wọ́n sí mímọ́. +Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli dìtẹ̀ sí mi ninu aṣálẹ̀, wọn kò pa òfin mi mọ́; wọ́n sì kọ ìlànà mi sílẹ̀, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè. Wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́ patapata. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata ninu aṣálẹ̀. +Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde. +Nítorí náà, mo búra fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n kò ní mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí pé n óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jù ní gbogbo ilẹ̀ ayé. +Nítorí pé wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọn kò tẹ̀lé òfin mi, wọ́n sì ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, nítorí pé ọkàn wọn kò kúrò lọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn. +“Sibẹsibẹ mo fojú àánú wò wọ́n, n kò pa wọ́n run sinu aṣálẹ̀. +Mo sọ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀ pé kí wọ́n má tọ ọ̀nà tí àwọn baba wọn rìn, kí wọ́n má ṣe tẹ̀lé òfin wọn, tabi kí wọ́n bọ oriṣa wọn. +Mo ní èmi OLUWA ni Ọlọrun yín. Ẹ máa rìn ní ọ̀nà mi, kí ẹ sì máa pa òfin mi mọ́. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +Ẹ máa pa àwọn ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín. +“Ṣugbọn, àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi: wọn kò tẹ̀lé ìlànà mi, wọn kò sì fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá tẹ̀lé ni yóo yè, wọ́n sì tún ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata, kí n tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lórí wọn ninu aṣálẹ̀. +Ṣugbọn mo rowọ́, mo sì ro ti orúkọ mi, tí n kò fẹ́ kí wọ́n bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde. +Nítorí náà, mo ṣe ìlérí fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n óo fọ́n wọn káàkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, +nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, wọn kò sì mójú kúrò lára àwọn oriṣa tí àwọn baba wọn ń bọ. +“Nítorí náà, mo fún wọn ní àṣẹ tí kò dára ati ìlànà tí kò lè gbà wọ́n là. +Mo jẹ́ kí ẹbọ wọn sọ wọ́n di aláìmọ́, mọ jẹ́ kí wọ́n máa sun àkọ́bí wọn ninu iná, kí ìpayà lè bá wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA. +“Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní Ọ̀nà mìíràn tí àwọn baba yín tún fi bà mí lórúkọ jẹ́ ni pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi. +Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra pé n óo fún wọn, bí wọ́n bá ti rí òkè kan tí ó ga, tabi tí wọ́n rí igi kan tí ewé rẹ̀ pọ̀, wọn a bẹ̀rẹ̀ sí gbé ẹbọ wọn kalẹ̀ sibẹ. Wọn a rú ẹbọ ìríra, wọn a mú kí òórùn dídùn ẹbọ wọn bo gbogbo ibẹ̀, wọ́n a sì bẹ̀rẹ̀ sí ta ohun mímu sílẹ̀. +Mo bi wọ́n léèrè pé irú ibi pẹpẹ ìrúbọ wo ni ẹ tilẹ̀ ń lọ ríì? Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní Bama títí di òní. +“Ìwọ ọmọ eniyan sọ fún àwọn àgbààgbà Israẹli pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ṣé ẹ wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi ni? Mo fi ara mi búra pé, n kò ní da yín lóhùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ +Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ṣé ẹ óo máa ba ara yín jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba yín, ẹ óo sì máa ṣìnà tẹ̀lé àwọn nǹkan ìríra wọn? +Ẹ̀ ń rú àwọn ẹbọ yín, ẹ sì ń fi àwọn ọmọkunrin yín rú ẹbọ sísun, ẹ sì ti fi oriṣa bíbọ ba ara yín jẹ́ títí di òní. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ẹ óo tún máa wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ mi? Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní rídìí ọ̀rọ̀ kankan lọ́dọ̀ mi. +Èrò ọkàn yín kò ní ṣẹ: ẹ̀ ń gbèrò ati dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ati àwọn ẹ̀yà tí ó wà ní agbègbè yín, kí ẹ máa bọ igi ati òkúta. +“Mo fi ara mi búra, dájúdájú, tipátipá, pẹlu ibinu ati ọwọ́ líle ni n óo fi jọba lórí yín. +N óo ko yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo ko yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti fi tipátipá fọ́n yín ká sí, pẹlu ọwọ́ líle, ati ibinu. +N óo ko yín lọ sinu aṣálẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, níbẹ̀ ni n óo ti dájọ́ yín lojukooju. +Bí mo ṣe dájọ́ àwọn baba ńlá yín ní aṣálẹ̀ ilẹ̀ Ijipti ni n óo dájọ́ yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“N óo mú kí ẹ gba abẹ́ ọ̀pá mi kọjá, n óo sì mu yín wá sí abẹ́ ìdè majẹmu. +N óo ṣa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn tí ń ṣe oríkunkun sí mi kúrò láàrin yín. N óo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò, ṣugbọn wọn kò ní dé ilẹ̀ Israẹli. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.” +Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA Ọlọrun ní, “Kí olukuluku yín lọ máa bọ oriṣa rẹ̀ láti ìsinsìnyìí lọ, bí ẹ kò bá fẹ́ gbọ́ tèmi, ṣugbọn ẹ kò ní fi ẹbọ ati oriṣa yín ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́. +“Ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan ìríra tí àwọn baba wọn ṣe. +Lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Israẹli, ni gbogbo ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli yóo ti máa sìn mí. Gbogbo yín pátá ní ilẹ̀ náà, ni ẹ óo máa sìn mí níbẹ̀. N óo yọ́nú si yín. N óo sì bèèrè ọrẹ àdájọ lọ́wọ́ yín ati ọrẹ àtinúwá tí ó dára jùlọ pẹlu ẹbọ mímọ́ yín. +N óo yọ́nú si yín bí ìgbà tí mo bá gbọ́ òórùn ẹbọ dídùn, nígbà tí mo bá ń ko yín jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mò ń ko yín jọ kúrò láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè tí ẹ fọ́nká sí. Ẹwà mímọ́ mi yóo sì hàn lára yín lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù. +Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ko yín dé ilẹ̀ Israẹli, ilẹ̀ tí mo búra láti fún àwọn baba ńlá yín. +Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, ẹ óo ranti ìṣe yín, ati gbogbo ìwà èérí tí ẹ hù tí ẹ fi ba ara yín jẹ́. Ojú ara yín yóo sì tì yín nígbà tí ẹ bá ranti gbogbo nǹkan burúkú tí ẹ ti ṣe. +Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ba yín wí nítorí orúkọ mi, tí kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwà burúkú yín tabi gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà burúkú yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA sọ fún mi pé, +“Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí ìhà gúsù, fi iwaasu bá ìhà ibẹ̀ wí, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ilẹ̀ igbó Nẹgẹbu. +Sọ fún igbó ibẹ̀ pé èmi OLUWA Ọlọrun ní n óo sọ iná sí i, yóo sì jó gbogbo àwọn igi inú rẹ̀, ati tútù ati gbígbẹ, iná náà kò ní kú. Yóo jó gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní gúsù títí dé àríwá. +Gbogbo eniyan ni yóo rí i pé èmi OLUWA ni mo dá iná náà, kò sì ní ṣe é pa.” +Mo bá dáhùn pé, “Áà! OLUWA Ọlọrun, wọ́n ń sọ nípa mi pé, ‘Ǹjẹ́ òun fúnrarẹ̀ kọ́ ni ó ń ro òwe yìí, tí ó sì ń pa á mọ́ wa?’ ” +Kí o sì sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní, ní ọjọ́ tí mo yan Israẹli, mo búra fún àwọn ọmọ Jakọbu, mo fi ara mi hàn fún wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo sì búra fún wọn pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn. +Ní ọjọ́ náà, mo búra fún wọn pé n óo yọ wọ́n kúrò ni ilẹ̀ Ijipti, n óo sì mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jùlọ láàrin gbogbo ilẹ̀ ayé. +Mo wí fún wọn pé kí olukuluku kọ àwọn nǹkan ẹ̀gbin tí ó gbójú lé sílẹ̀, kí ẹ má sì fi àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti, ba ara yín jẹ́; nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. +Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, wọn kò sì gbọ́ tèmi, ẹnìkankan ninu wọn kò mójú kúrò lára àwọn ère tí wọ́n ń bọ tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ àwọn oriṣa Ijipti sílẹ̀. Mo kọ́ rò ó pé kí n bínú sí wọn, kí n sì tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn ní ilẹ̀ Ijipti. +Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ láàrin àwọn eniyan tí wọn ń gbé, lójú àwọn tí mo ti fi ara mi hàn wọ́n ní ilẹ̀ Ijipti, nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò níbẹ̀. +Ìfẹ́ OLUWA ati Àìbìkítà Eniyan. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní, +A ti pọ́n ọn láti fi paniyan;a ti fi epo pa á, kí ó lè máa kọ mànà bíi mànàmáná.Ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ àríyá;nítorí àwọn eniyan mi kọ̀, wọn kò náání ìkìlọ̀ ati ìbáwí mi. +Nítorí náà, a pọ́n idà náà, a sì fi epo pa á,kí á lè fi lé ẹni tí yóo fi paniyan lọ́wọ́. +Ìwọ ọmọ eniyan, kígbe, kí o sì pohùnréré ẹkún,nítorí àwọn eniyan mi ni a yọ idà sí;ati àwọn olórí ní Israẹli.Gbogbo wọn ni a óo fi idà pa pẹlu àwọn eniyan mi.Nítorí náà káwọ́ lérí kí o sì máa hu. +Mò ń dán àwọn eniyan mi wò,bí wọ́n bá sì kọ̀, tí wọn kò ronupiwada,gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn,Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀, kí o sápẹ́, fi idà lalẹ̀ léraléra, idà tí a fà yọ tí a fẹ́ fi paniyan. Idà tí yóo pa ọ̀pọ̀ eniyan ní ìpakúpa, tí ó sì súnmọ́ tòsí wọn pẹ́kípẹ́kí. +Kí àyà wọn lè já, kí ọpọlọpọ lè kú ní ẹnubodè wọn. Mo ti fi idà tí ń dán lélẹ̀ fún pípa eniyan, ó ń kọ mànà bíi mànàmáná, a sì ti fi epo pa á. +Máa pa wọ́n lọ ní ọwọ́ ọ̀tún, ati ní ọwọ́ òsì, níbikíbi tí ó bá sá ti kọjú sí. +Èmi náà yóo máa pàtẹ́wọ́, inú tí ń bí mi yóo sì rọ̀, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +“Ìwọ ọmọ eniyan, la ọ̀nà meji fún idà ọba Babiloni láti gbà wọ̀lú, kí ọ̀nà mejeeji wá láti ilẹ̀ kan náà. Fi atọ́ka sí oríta níbi tí ọ̀nà ti yà wọ ìlú. +“Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí Jerusalẹmu kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ibi mímọ́ Israẹli. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli. +La ọ̀nà fún idà kan láti gbà wọ ìlú Raba ní ilẹ̀ Amoni, kí o sì la ọ̀nà mìíràn fún idà láti gbà wọ ilẹ̀ Juda ati ìlú Jerusalẹmu tí a mọ odi yíká. +Nítorí pé ọba Babiloni ti dúró sí oríta, ní ibi tí ọ̀nà ti pínyà; ó dúró láti ṣe àyẹ̀wò. Ó mi ọfà, ó bá oriṣa sọ̀rọ̀, ó sì woṣẹ́ lára ẹ̀dọ̀ ẹran. +Ọfà ìbò Jerusalẹmu yóo bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Yóo kígbe, àwọn eniyan náà yóo sì kígbe sókè. Wọn óo gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ìlẹ̀kùn ti ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀, wọn yóo mọ òkítì sí ara odi rẹ̀, wọn yóo sì mọ ilé ìṣọ́ tì í. +Gbogbo ohun tí ó ń ṣe yóo dàbí ẹni tí ń dífá irọ́ lójú àwọn ará ìlú, nítorí pé majẹmu tí wọ́n ti dá yóo ti kì wọ́n láyà; ṣugbọn ọba Babiloni yóo mú wọn ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, yóo ṣẹgun wọn yóo sì kó wọn lọ. +Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ní, ẹ ti jẹ́ kí n ranti ẹ̀ṣẹ̀ yín, nítorí pé ẹ ti tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ninu gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ yín ti hàn; ogun yóo ko yín nítorí pé ẹ ti mú kí n ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín. +“Ìwọ olórí Israẹli, aláìmọ́ ati ẹni ibi, ọjọ́ rẹ pé; àkókò ìjìyà ìkẹyìn rẹ sì ti tó. +Ẹ ṣí fìlà, kí ẹ sì ṣí adé ọba kúrò lórí, gbogbo nǹkan kò ní wà bí wọ́n ṣe rí. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ gbé àwọn tí ipò wọn rẹlẹ̀ ga, kí ẹ sì rẹ àwọn tí ipò wọn wà lókè sílẹ̀. +Ìparun! Ìparun! N óo pa ìlú yìí run ni; ṣugbọn n kò ní tíì pa á run, títí ẹni tí ó ni í yóo fi dé, tí n óo sì fi lé e lọ́wọ́. +“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Amoni ati ẹ̀gàn wọn nìyí:‘A ti fa idà yọ, láti paniyan.A ti fi epo pa á kí ó lè máa dán, kí ó sì máa kọ mànà bíi mànàmáná. +Nígbà tí wọn ń ríran èké, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́ fún ọ, a óo gbé idà náà lé ọrùn àwọn aláìmọ́ ati ẹni ibi, tí ọjọ́ wọn ti pé, àní ọjọ́ ìjìyà ìkẹyìn wọn. +Sọ fún ilẹ̀ náà pé OLUWA ní, ‘Wò ó, mo ti dojú kọ ọ́, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì pa àwọn eniyan inú rẹ: ati àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú. +“ ‘Dá idà náà pada sinu àkọ̀ rẹ̀. Ní ilẹ̀ rẹ ní ibi tí a ti dá ọ, ni n óo ti dá ọ lẹ́jọ́. +N óo bínú sí ọ lọpọlọpọ, ìrúnú mi yóo jó ọ bí iná, n óo fà ọ́ lé àwọn oníjàgídíjàgan lọ́wọ́, àwọn tí wọ́n mọ̀ bí wọ́n ṣe ń panirun. +O óo di nǹkan ìdáná, lórí ilẹ̀ yín ni a óo pa yín sí, ẹ óo sì di ẹni ìgbàgbé, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” +N óo pa àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú tí ó wà ninu rẹ run, nítorí náà, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo eniyan láti ìhà gúsù títí dé ìhà àríwá. +Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo fa idà mi yọ, n kò sì ní dá a pada sinu àkọ̀ mọ́.’ +“Ìwọ ọmọ eniyan, máa mí ìmí ẹ̀dùn, bí ẹni tí ọkàn rẹ̀ ti dàrú, tí ó sì ń kẹ́dùn níwájú wọn. +Bí wọ́n bá bi ọ́ pé kí ló dé tí o fi ń mí ìmí ẹ̀dùn, sọ fún wọn pé nítorí ìròyìn tí o gbọ́ ni. Nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀, ọkàn gbogbo eniyan yóo dàrú, ọwọ́ wọn yóo rọ ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá wọn, ẹsẹ̀ wọn kò ní ranlẹ̀ mọ́. Wò ó! Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé èmi: OLUWA Ọlọrun ní:Ẹ wo idà, àní idà tí a ti pọ́n, tí a sì ti fi epo pa. +Idà OLUWA. +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +Àwọn mìíràn ń bá aya baba wọn lòpọ̀, wọ́n sì ń fi ipá bá obinrin lòpọ̀ ní ìgbà tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́. +Ẹnìkínní ń bá aya ẹnìkejì rẹ̀ lòpọ̀; àwọn kan ń bá aya ọmọ wọn lòpọ̀; ẹ̀gbọ́n ń bá àbúrò rẹ̀ lòpọ̀, àwọn mìíràn sì ń bá ọbàkan wọn lòpọ̀ ninu rẹ, Jerusalẹmu. +Wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti paniyan láàrin ìlú, wọ́n ń gba owó èlé, ẹ̀ ń ní àníkún, ẹ sì ń fi ipá gba owó lọ́wọ́ aládùúgbò yín, ẹ ti gbàgbé mi, èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Nítorí náà mo pàtẹ́wọ́ le yín lórí nítorí èrè aiṣootọ tí ẹ̀ ń jẹ ati eniyan tí ẹ̀ ń pa ninu ìlú. +Ǹjẹ́ o lè ní ìgboyà ati agbára ní ọjọ́ tí n óo bá jẹ ọ́ níyà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe. +N óo fọn yín káàkiri ààrin àwọn àjèjì; n óo tu yín ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo fi òpin sí ìwà èérí tí ẹ̀ ń hù ní Jerusalẹmu. +N óo di ẹni ìdọ̀tí lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn nítorí rẹ, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +“Ìwọ ọmọ eniyan; àwọn ọmọ Israẹli ti di ìdàrọ́ lójú mi. Wọ́n dàbí idẹ, páànù, irin, ati òjé tí ó wà ninu iná alágbẹ̀dẹ. Wọ́n dàbí ìdàrọ́ ara fadaka. +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní níwọ̀n ìgbà tí gbogbo yín ti di ìdàrọ́, n óo ko yín jọ sí ààrin Jerusalẹmu. +“Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o óo dájọ́, ṣé o óo dájọ́ ìlú tí ó kún fún ìpànìyàn yìí? Sọ gbogbo ìwà ìríra rẹ̀ fún un. +Bí eniyan ṣe ń kó fadaka, idẹ, irin, òjé ati páànù pọ̀ sinu ìkòkò lórí iná alágbẹ̀dẹ, kí wọ́n lè yọ́, bẹ́ẹ̀ ni n óo fi ibinu ati ìrúnú ko yín jọ n óo sì yọ yín. +N óo ko yín jọ, n óo fẹ́ ìrúnú mi si yín lára bí iná, ẹ óo sì yọ́. +Bí wọn tí ń yọ́ fadaka ninu iná alágbẹ̀dẹ, bẹ́ẹ̀ ni n óo fi ibinu yọ yín, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo bínú si yín.” +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ilẹ̀ tí kò mọ́ ni ilẹ̀ wọn, ilẹ̀ tí òjò kò rọ̀ sí lákòókò ibinu èmi OLUWA. +Àwọn olórí tí wọ́n wà nílùú dàbí kinniun tí ń bú, tí ó sì ń fa ẹran ya. Wọ́n ti jẹ àwọn eniyan run, wọ́n ń fi ipá já ohun ìní ati àwọn nǹkan olówó iyebíye gbà, wọ́n ti sọ ọpọlọpọ obinrin di opó nílùú. +Àwọn alufaa rẹ̀ ti kọ òfin mi sílẹ̀, wọ́n ti sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́. Wọn kò fi ìyàtọ̀ sáàrin àwọn nǹkan mímọ́ ati nǹkan àìmọ́; wọn kò sì kọ́ àwọn eniyan ní ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin nǹkan mímọ́ ati àìmọ́. Wọn kò bìkítà fún ọjọ́ ìsinmi mi, mo sì ti di aláìmọ́ láàrin wọn. +Àwọn olórí tí ó wà ninu wọn dàbí ìkookò tí ń fa ẹran ya, wọ́n ń pa eniyan, wọ́n sì ń run eniyan láti di olówó. +Àwọn wolii wọn ń tàn wọ́n, wọ́n ń ríran irọ́, wọ́n ń woṣẹ́ èké. Wọ́n ń wí pé, OLUWA sọ báyìí, báyìí; bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò sọ nǹkankan. +Àwọn eniyan ilẹ̀ náà ń fi ipá gba nǹkan-oní-nǹkan; wọ́n ń ni talaka ati aláìní lára, wọ́n sì ń fi ipá gba nǹkan lọ́wọ́ àwọn àlejò láì ṣe àtúnṣe. +Sọ fún un pé èmi OLUWA Ọlọrun ní, ìwọ ìlú tí wọ́n ti ń paniyan ní ìpakúpa kí àkókò ìjìyà rẹ̀ lè tètè dé, ìlú tí ń fi oriṣa ba ara rẹ̀ jẹ́! +Mo wá ẹnìkan láàrin wọn tí ìbá tún odi náà mọ, kí ó sì dúró níbi tí odi ti ya níwájú mi láti bẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, kí n má baà pa á run, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan. +Nítorí náà, n óo bínú sí wọn; n óo fi ìrúnú pa wọ́n rẹ́, n óo sì gbẹ̀san ìwà wọn lára wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +A ti dá ọ lẹ́bi nítorí àwọn eniyan tí o pa, o sì ti di aláìmọ́ nítorí àwọn ère tí o gbẹ́. O ti mú kí ọjọ́ ìjìyà rẹ súnmọ́ tòsí, ọdún tí a dá fún ọ sì pé tán. Nítorí náà, mo ti sọ ọ́ di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn eniyan, ati ẹni yẹ̀yẹ́ lójú gbogbo orílẹ̀-èdè. +Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n súnmọ́ ọ ati àwọn tí wọ́n jìnnà sí ọ yóo máa fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́, ìwọ tí o kò níyì, tí o kún fún ìdàrúdàpọ̀. +Wo àwọn olórí ní ilẹ̀ Israẹli tí wọ́n wà ninu rẹ, olukuluku ti pinnu láti máa lo agbára rẹ̀ láti máa paniyan. +Àwọn ọmọ kò náání baba ati ìyá wọn ninu rẹ; wọ́n sì ń ni àwọn àjèjì ninu rẹ lára; wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn aláìníbaba ati opó. +O kò bìkítà fún àwọn ohun mímọ́ mi, o sì ti ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. +Àwọn eniyan inú rẹ ń parọ́ láti paniyan. Wọ́n ń jẹbọ kiri lórí àwọn òkè ńláńlá, wọ́n sì ń ṣe ohun ìtìjú. +Ìwà Ibi Jerusalẹmu. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +Wọ́n tú aṣọ lára rẹ̀, wọ́n kó àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin; wọ́n sì fi idà pa òun alára. Orúkọ rẹ̀ wá di yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn obinrin nígbà tí ìdájọ́ dé bá a. +“Oholiba, àbúrò rẹ̀ rí èyí, sibẹsibẹ, ojú ṣíṣẹ́ sí ọkunrin ati àgbèrè tirẹ̀ burú ju ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ. +Ó ń ṣẹ́jú sí àwọn ará Asiria: àwọn gomina ati àwọn ọ̀gágun, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n di ihamọra, tí wọn ń gun ẹṣin, ọdọmọkunrin ni gbogbo wọn, ojú wọn fanimọ́ra. +Mo rí i pé ó ti ba ara rẹ̀ jẹ́, ọ̀nà kan náà ni àwọn mejeeji jọ ń tọ̀. +“Ṣugbọn ìwà àgbèrè tirẹ̀ ju ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ. Nígbà tí ó rí àwòrán àwọn ọkunrin, ará Kalidea tí a fi ọ̀dà pupa kùn lára ògiri, +tí wọ́n di àmùrè, tí wọ́n wé lawani gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀, tí gbogbo wọn dàbí ọ̀gá àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun, àwọn ọmọ ogun ará Babilonia. +Bí ó ti rí wọn, wọ́n wọ̀ ọ́ lójú, ó bá rán ikọ̀ sí wọn ní ilẹ̀ Kalidea. +Àwọn ará Babiloni bá tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bá a ṣeré ìfẹ́ lórí ibùsùn rẹ̀, wọ́n sì fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn bà á jẹ́. Nígbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn pẹlu ìríra. +Nígbà tí ó ń ṣe àgbèrè ní gbangba, tí ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò, mo yipada kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu ìríra, bí mo ti yipada kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. +Sibẹ ó tún fi kún ìwà àgbèrè rẹ̀, nígbà tí ó ranti àgbèrè ìgbà èwe rẹ̀ ní ilẹ̀ Ijipti. +“Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọmọbinrin meji kan wà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá kan náà. +Ó kún fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fún àwọn ọkunrin tí ojú ara wọn dàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, nǹkan ọkunrin wọn sì dàbí ti ẹṣin.” +O tún fẹ́ láti máa ṣe ìṣekúṣe tí o ṣe nígbà èwe rẹ, tí àwọn ọkunrin Ijipti ń dì mọ́ ọ lẹ́gbẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ń fi ọwọ́ fún ọ ní ọmú ọmọge. +Nítorí náà, Oholiba, OLUWA Ọlọrun ní, “Mo ṣetán tí n óo gbé àwọn olùfẹ́ rẹ dìde, àwọn tí o kọ̀ sílẹ̀ nítorí ìríra. N óo mú wọn dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà: +àwọn ará Babiloni ati gbogbo àwọn ará Kalidea láti Pekodi, ati Ṣoa ati Koa, pẹlu gbogbo àwọn ará Asiria: àwọn ọdọmọkunrin tí ojú wọn fanimọ́ra, àwọn gomina, ati àwọn ọ̀gágun, tí gbogbo wọn jẹ́ olórí ogun, tí wọ́n sì ń gun ẹṣin. +Wọn óo dojú kọ ọ́ láti ìhà àríwá, pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun, kẹ̀kẹ́ ẹrù, ati ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun. Wọn óo gbógun tì ọ́ ní gbogbo ọ̀nà pẹlu apata, asà ati àkẹtẹ̀ ogun. N óo fi ìdájọ́ rẹ lé wọn lọ́wọ́, òfin ilẹ̀ wọn ni wọn óo sì tẹ̀lé tí wọn óo fi dá ọ lẹ́jọ́. +N óo dojú kọ ọ́ pẹlu ibinu, n óo jẹ́ kí wọ́n fi ìrúnú bá ọ jà. Wọn óo gé ọ ní etí ati imú, wọn óo sì fi idà pa àwọn eniyan rẹ tí wọ́n kù. Wọn óo kó àwọn ọmọ rẹ ọkunrin ati obinrin lọ, wọn óo sì dáná sun àwọn tí wọ́n kù. +Wọn yóo bọ́ aṣọ lára rẹ; wọn yóo kó gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ rẹ lọ. +Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí ìṣekúṣe ati àgbèrè tí o kó ti ilẹ̀ Ijipti wá. O kò ní ṣíjú wo àwọn ará Ijipti mọ́, o kò sì ní ranti wọn mọ́.” +OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ọ́ lé àwọn tí o kórìíra lọ́wọ́, àwọn tí ọkàn rẹ yipada kúrò lọ́dọ̀ wọn pẹlu ìríra. +Ìkórìíra ni wọn yóo fi máa bá ọ gbé, wọn yóo kó gbogbo èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lọ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò goloto. Wọn yóo tú ọ sí ìhòòhò, gbogbo ayé yóo sì mọ̀ pé aṣẹ́wó ni ọ́. Ìṣekúṣe ati àgbèrè rẹ ni +Wọ́n lọ ṣe aṣẹ́wó ní ilẹ̀ Ijipti nígbà tí wọ́n jẹ́ ọmọge. Àwọn kan fọwọ́ fún wọn lọ́mú, wọ́n fọwọ́ pa orí ọmú wọn nígbà tí wọn kò tíì mọ ọkunrin. +ó mú èyí wá sórí rẹ, nítorí o ti bá àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe àgbèrè, o sì ti fi oriṣa wọn ba ara rẹ jẹ́. +Ìwà tí ẹ̀gbọ́n rẹ hù ni ìwọ náà ń hù, nítorí náà, ìyà tí mo fi jẹ ẹ̀gbọ́n rẹ ni n óo fi jẹ ìwọ náà.” +OLUWA Ọlọrun ní:“ọpọlọpọ ìyà tí mo fi jẹ ẹ̀gbọ́n rẹ ni n óo fi jẹ ọ́,wọn óo fi ọ́ rẹ́rìn-ín,wọn óo sì fi ọ́ ṣẹ̀sín,nítorí ìyà náà óo pọ̀. +Ìyà óo jẹ ọ́ lọpọlọpọ,ìbànújẹ́ óo sì dé bá ọ.N óo mú ìpayà ati ìsọdahoro bá ọ,bí mo ṣe mú un bá Samaria, ẹ̀gbọ́n rẹ. +O óo jìyà ní àjẹtẹ́rùn,tóbẹ́ẹ̀ tí o óo máa fi àkúfọ́ àwo ìyà tí o bá jẹ ya ara rẹ lọ́mú.Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí pé o ti gbàgbé mi, o sì ti kọ̀ mí sílẹ̀, o óo jìyà ìṣekúṣe ati àgbèrè rẹ.” +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan ṣé o óo dá ẹjọ́ Ohola ati Oholiba? Nítorí náà fi ìwà ìríra tí wọ́n hù hàn wọ́n. +Nítorí wọ́n ti ṣe àgbèrè, wọ́n sì ti paniyan; wọ́n ṣe àgbèrè ẹ̀sìn lọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn, wọ́n sì ti pa àwọn ọmọ wọn ọkunrin tí wọ́n bí fún mi, bọ oriṣa wọn. +Èyí nìkan kọ́ ni wọ́n ṣe sí mi, wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di eléèérí, wọ́n sì ba àwọn ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. +Ní ọjọ́ náà gan-an tí wọ́n pa àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n fi wọ́n rúbọ sí oriṣa wọn, ni wọ́n tún wá sí ilé ìsìn mi, tí wọ́n sọ ọ́ di eléèérí. Wò ó! Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ní ilé mi. +Orúkọ ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Ohola, ti àbúrò sì ń jẹ́ Oholiba. Àwọn mejeeji di tèmi; wọ́n sì bímọ lọkunrin ati lobinrin. Èyí tí ń jẹ́ Ohola ni Samaria, èyí tí ń jẹ́ Oholiba ni Jerusalẹmu. +“Wọ́n tilẹ̀ tún ranṣẹ lọ pe àwọn ọkunrin wá láti òkèèrè, oníṣẹ́ ni wọ́n gbé dìde kí ó lọ pè wọ́n wá; àwọn náà sì wá. Nígbà tí wọ́n dé, ẹ wẹ̀, ẹ kun àtíkè, ẹ tọ́ ojú, ẹ sì ṣe ara yín lọ́ṣọ̀ọ́. +Ẹ jókòó lórí àga ọlọ́lá. Ẹ tẹ́ tabili siwaju; ẹ wá gbé turari ati òróró mi lé e lórí. +Ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìbìkítà ẹ̀dá bẹ̀rẹ̀ sí pariwo lọ́dọ̀ yín, àwọn ọkunrin ọ̀mùtí lásánlàsàn kan sì wá láti inú aṣálẹ̀, wọ́n kó ẹ̀gbà sí àwọn obinrin lọ́wọ́, wọ́n fi adé tí ó lẹ́wà dé wọn lórí. +Nígbà náà ni mo wí lọ́kàn ara mi pé, Ǹjẹ́ àwọn ọkunrin wọnyi kò tún ń ṣe àgbèrè, pẹlu àwọn obinrin panṣaga burúkú yìí? +Nítorí wọ́n ti tọ̀ wọ́n lọ bí àwọn ọkunrin tí ń tọ aṣẹ́wó lọ. Wọ́n wọlé tọ Ohola ati Oholiba lọ, wọ́n sì bá wọn ṣe àgbèrè. +Ṣugbọn àwọn olódodo eniyan ni yóo dá àwọn obinrin náà lẹ́jọ́ panṣaga, ati ti apànìyàn, nítorí pé panṣaga eniyan ni wọ́n, wọ́n sì ti paniyan.” +Nítorí pé OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ pe ogunlọ́gọ̀ eniyan lé wọn lórí kí wọ́n ṣẹ̀rù bà wọ́n, kí wọ́n sì kó wọn lẹ́rù; +kí ogunlọ́gọ̀ eniyan wọnyi óo sọ wọ́n lókùúta, wọn óo sì gún wọn ní idà. Wọn óo pa àwọn ọmọ wọn; tọkunrin tobinrin, wọn óo sì dáná sun ilé wọn. +Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí ìṣekúṣe ní ilẹ̀ náà; èyí óo sì kọ́ gbogbo àwọn obinrin lẹ́kọ̀ọ́, pé kí wọ́n má máa ṣe ìṣekúṣe bíi tiyín. +N óo da èrè ìṣekúṣe yín le yín lórí, ẹ óo sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà yín. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.” +Ohola tún lọ ṣe àgbèrè lẹ́yìn tí ó ti di tèmi, ó tún ń ṣẹ́jú sí àwọn ará Asiria, olólùfẹ́ rẹ̀: +àwọn ọmọ ogun tí wọn ń wọ aṣọ àlàárì, àwọn gomina ati àwọn ọ̀gágun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin, ọdọmọkunrin ni gbogbo wọn, ojú wọn sì fanimọ́ra. +Ó bá gbogbo àwọn eniyan pataki pataki Asiria ṣe àgbèrè, ó sì fi oriṣa gbogbo àwọn tí ó ń ṣẹ́jú sí ba ara rẹ̀ jẹ́. +Kò kọ ìwà àgbèrè rẹ̀ tí ó ń hù nígbà tí ó ti wà ní ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀. Nígbà èwe rẹ̀, àwọn ọkunrin bá a lòpọ̀, wọ́n fọwọ́ pa á lọ́mú, wọ́n sì tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn lára rẹ̀. +Nítorí gbogbo èyí, mo fi lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, àwọn ará Asiria tí ó ń ṣẹ́jú sí. +Àwọn Arabinrin Tí Wọ́n Jẹ́ Ẹlẹ́ṣẹ̀. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ kẹwaa, oṣù kẹwaa, ọdún kẹsan-an tí a ti wà ní ìgbèkùn, ó ní, +Ẹ kó ọpọlọpọ igi jọ; ẹ ṣáná sí i. Ẹ se ẹran náà dáradára, ẹ da omi rẹ̀ nù, kí ẹ jẹ́ kí egungun rẹ̀ jóná. +Lẹ́yìn náà, ẹ gbé òfìfo ìkòkò náà léná, kí ó gbóná, kí idẹ inú rẹ̀ lè yọ́; kí ìdọ̀tí tí ó wà ninu rẹ̀ lè jóná, kí ìpẹtà rẹ̀ sì lè jóná pẹlu. +Lásán ni mò ń ṣe wahala, gbogbo ìpẹtà náà kò ní jóná. +Jerusalẹmu, ìṣekúṣe ti dípẹtà sinu rẹ, mo fọ̀ ọ́ títí, ìdọ̀tí kò kúrò ninu rẹ, kò sì ní kúrò mọ́ títí n óo fi bínú sí ọ tẹ́rùn. +Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Bí mo ti wí ni n óo ṣe, n kò ní dáwọ́ dúró, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yí ọkàn pada. Ìwà ati ìṣe yín ni n óo fi da yín lẹ́jọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! Mo ṣetán tí n óo gba ohun tí ń dùn ọ́ ninu lọ́wọ́ rẹ. Lójijì ni n óo gbà á, o kò sì gbọdọ̀ banújẹ́ tabi kí o sọkún, bẹ́ẹ̀ ni omi kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀ lójú rẹ. +O lè mí ìmí ẹ̀dùn, ṣugbọn a kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn rẹ, o kò sì gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀. Wé lawani mọ́rí, sì wọ bàtà. O kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu, o kò sì gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀.” +Mo bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ láàárọ̀, nígbà tí ó di àṣáálẹ́, iyawo mi kú. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ pé kí n ṣe. +Àwọn eniyan bá bi mí pé, “Ṣé kò yẹ kí o sọ ohun tí nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí túmọ̀ sí fún wa, tí o fi ń ṣe báyìí.” +“Ìwọ ọmọ eniyan, sàmì sí ọjọ́ òní, kọ orúkọ ọjọ́ òní sílẹ̀. Lónìí gan-an ni ọba Babilonia gbógun ti Jerusalẹmu. +Mo bá sọ fún wọn pé, “OLUWA ni ó bá mi sọ̀rọ̀, +tí ó ní kí n sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé òun OLUWA sọ pé òun óo sọ ibi mímọ́ òun di aláìmọ́: ibi mímọ́ òun tí ẹ fi ń ṣògo, tí ó jẹ́ agbára yín, tí ẹ fẹ́ràn láti máa wò, tí ọkàn yín sì fẹ́. Ogun yóo pa àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín tí ẹ fi sílẹ̀. +Bí mo ti ṣe yìí gan-an ni ẹ̀yin náà gbọdọ̀ ṣe, ẹ kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu yín tabi kí ẹ máa jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀. +Lawani yín gbọdọ̀ wà lórí yín; kí bàtà yín sì wà ní ẹsẹ̀ yín, ẹ kò gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ tabi kí ẹ sọkún. Ẹ óo joró nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ óo sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ tẹ̀dùntẹ̀dùn. +Ó ní èmi Isikiẹli óo jẹ́ àmì fun yín, gbogbo bí mo bá ti ṣe ni ẹ̀yin náà gbọdọ̀ ṣe nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹlẹ̀. Ẹ óo sì mọ̀ pé òun ni OLUWA Ọlọrun.” +OLUWA ní, “Ìwọ ní tìrẹ, ọmọ eniyan, ní ọjọ́ tí mo bá gba ibi ààbò wọn lọ́wọ́ wọn, àní ayọ̀ ati ògo wọn, ohun tí wọ́n fẹ́ máa rí, tí ọkàn wọn sì fẹ́, pẹlu àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin, +ní ọjọ́ náà, ẹnìkan tí yóo sá àsálà ni yóo wá fún ọ ní ìròyìn. +Ní ọjọ́ náà, ẹnu rẹ óo yà, o óo sì le sọ̀rọ̀; o kò ní ya odi mọ́. Ìwọ ni o óo jẹ́ àmì fún wọn; wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +Pa òwe yìí fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi kí o sì wí fún wọn pé, ní orúkọ èmi OLUWA Ọlọrun: Gbé ìkòkò kaná;bu omi sí i. +Kó ègé ẹran sí i,gbogbo ibi tí ó dára jùlọ lára ẹran,ẹran itan ati ti èjìká,kó egungun tí ó dára náà sí i kí ó kún. +Ẹran tí ó dára jùlọ ninu agbo ni kí o mú,kó igi jọ sí abẹ́ ìkòkò náà,kí o bọ ẹran náà,bọ̀ ọ́ teegunteegun.” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ègbé ni fún ìlú apànìyàn, ìkòkò tí inú rẹ̀ dípẹtà, tí ìdọ̀tí rẹ̀ kò ṣí kúrò ninu rẹ̀! Yọ ẹran inú rẹ̀ kúrò lọ́kọ̀ọ̀kan, sá máa mú èyí tí ọwọ́ rẹ bá ti bà. +Nítorí pé ẹ̀jẹ̀ eniyan tí ó pa wà ninu rẹ̀, orí àpáta ni ó da ẹ̀jẹ̀ wọn sí, kò dà á sórí ilẹ̀, tí yóo fi rí erùpẹ̀ bò ó. +Mo ti da ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ sórí àpáta, kí ó má baà ṣe é bò mọ́lẹ̀. Kí inú lè bí mi, kí n lè gbẹ̀san.” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ègbé ni fún ìlú tí ó kún fún ìpànìyàn yìí, èmi fúnra mi ni n óo kó iná ńlá jọ. +Ìkòkò Ìdáná tí Ó Dípẹtà. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +N óo fún àwọn ará ìlà oòrùn ní òun ati ilẹ̀ Amoni, wọn óo di ìkógun, kí á má baà ranti rẹ̀ mọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. +N óo ṣe ìdájọ́ àwọn ará Moabu; wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA!” +OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí àwọn ará Edomu gbẹ̀san lára àwọn ará Juda, wọ́n sì ṣẹ̀ nítorí ẹ̀san tí wọ́n gbà. +N óo nawọ́ ìyà sí Edomu, n óo pa ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀ run. N óo sọ ọ́ di ahoro láti Temani títí dé Dedani. Ogun ni yóo pa wọ́n. +Àwọn eniyan mi, Israẹli, ni n óo lò láti gbẹ̀san lára Edomu. Bí inú ti bí mi tó, ati bí inú mi ṣe ń ru tó, ni wọn yóo ṣe fi ìyà jẹ Edomu. Wọn óo wá mọ̀ bí mo ti lè gbẹ̀san tó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Àwọn ará Filistia gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn, wọn sì fi ìkórìíra àtayébáyé pa wọ́n run, +nítorí náà, n óo nawọ́ ìyà sí wọn, n óo pa àwọn ọmọ Kereti run, n óo pa àwọn tí ó kù sí etí òkun rẹ́. +N óo gbẹ̀san lára wọn lọpọlọpọ; n óo fi ìrúnú fi ìyà ńlá jẹ wọ́n. Wọn óo wá mọ̀ nígbà tí mo bá gbẹ̀san lára wọn pé èmi ni OLUWA.” +“Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí àwọn ará Amoni kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn. +Wí fún wọn báyìí pé, ‘Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun wí; nítorí pé ẹ̀ ń yọ̀ nígbà tí wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, ati pé ẹ̀ ń yọ ilẹ̀ Israẹli, nígbà tí wọ́n sọ ọ́ di ahoro, ẹ sì ń yọ ilẹ̀ Juda, nígbà tí wọ́n kó o lọ sí ìgbèkùn; +nítorí náà, n óo fà yín lé àwọn ará ilẹ̀ ìlà oòrùn lọ́wọ́, ẹ óo sì di tiwọn. Wọn óo pa àgọ́ sí ààrin yín; wọn óo tẹ̀dó sí ààrin yín; wọn óo máa jẹ èso oko yín, wọn óo sì máa mu wàrà yín. +N óo sọ ìlú Raba di pápá àwọn ràkúnmí, àwọn ìlú Amoni yóo sì di pápá ẹran. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA!’ +Nitori báyìí ni OLUWA Ọlọrun wí, “Ẹ̀yin ń pàtẹ́wọ́, ẹ̀ ń fò sókè, ẹ sì ń yọ àwọn ọmọ Israẹli. +Nítorí náà, ẹ wò ó! Mo ti nawọ́ ìyà si yín, n óo sì fi yín ṣe ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. N óo pa yín run láàrin àwọn eniyan ilẹ̀ ayé, n óo sì pa yín rẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Àwọn ará Moabu ń wí pé ilẹ̀ Juda dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, +nítorí náà, n óo tú àwọn ìlú Moabu tí wọ́n wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì ká: àwọn ìlú tí ó dára jù ní ilẹ̀ Moabu, Beti Jẹṣimoti, Baali Meoni ati Kiriataimu ká. +Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Amoni. +Ní ọjọ́ kinni oṣù, ní ọdún kọkanla tí a dé ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀: ó ní, +Ẹṣin rẹ̀ óo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí eruku ẹsẹ̀ wọn yóo bò ọ́ mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dé ẹnubodè rẹ, ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ ati ti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù ati ti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo mi odi rẹ tìtì, nígbà tí wọ́n bá dé ẹnubodè rẹ, bí ìgbà tí àwọn ọmọ ogun bá wọ ìlú tí odi rẹ̀ ti wó. +Yóo fi pátákò ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin rẹ̀ tú gbogbo ilẹ̀ ìgboro rẹ, yóo fi idà pa àwọn eniyan rẹ; yóo sì wó àwọn òpó ńláńlá rẹ lulẹ̀. +Yóo kó ọrọ̀ rẹ ati àwọn ọjà tí ò ń tà ní ìkógun. Yóo wó odi rẹ ati àwọn ilé dáradára tí ó wà ninu rẹ lulẹ̀. Yóo ru òkúta, ati igi, ati erùpẹ̀ tí ó wà ninu ìlú rẹ dà sinu òkun. +N óo wá fi òpin sí orin kíkọ ninu rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn dùùrù ninu rẹ mọ́. +N óo sì sọ ọ́ di àpáta lásán, o óo di ibi tí wọn óo máa sá àwọ̀n sí; ẹnikẹ́ni kò sì ní tún ọ kọ́ mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA Ọlọrun sọ fún ìlú Tire pé, “Ǹjẹ́ gbogbo ilẹ̀ tí ó wà létí òkun kò ní mì tìtì nítorí ìṣubú rẹ, nígbà tí àwọn tí wọ́n farapa bá ń kérora, tí a sì pa ọpọlọpọ ní ìpakúpa ninu rẹ? +Gbogbo àwọn ọba ìlú etí òkun yóo sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn óo bọ́ aṣọ ìgúnwà wọn, ati agbádá ọlọ́nà tí wọ́n wọ̀, jìnnìjìnnì óo dà bò wọ́n, wọn óo jókòó sórí ilẹ̀, wọn óo bẹ̀rẹ̀ sí máa gbọ̀n, ẹnu óo sì yà wọ́n nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ. +Wọn yóo wá dá orin arò fún ọ pé:Wò ó bí o ti parẹ́ ninu òkun,ìwọ ìlú olókìkí,ìwọ ìlú tí ó lágbára lórí òkun,ìwọ ati àwọn tí ń gbé inú rẹ,àwọn tí wọn ń mú kí ẹ̀rù rẹ máa ba àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀. +Àwọn erékùṣù yóo wárìrì ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.Nítòótọ́, àwọn erékùṣù tí wọ́n wà ninu òkun yóo dààmú nítorí ìparun rẹ.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ìparun bí àwọn ìlú tí ẹnìkan kò gbé inú rẹ̀, nígbà tí mo bá mú kí omi òkun bò ọ́ mọ́lẹ̀, tí ibú omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀, +“Ìwọ ọmọ eniyan, nítorí pé àwọn ará ìlú Tire ń yọ̀ sí ìṣubú ìlú Jerusalẹmu, wọ́n ń sọ wí pé ìlẹ̀kùn ibodè àwọn eniyan yìí ti já, ibodè wọn sì ti ṣí sílẹ̀ fún wa, nisinsinyii tí ó di àlàpà, a óo ní àníkún. +n óo fà ọ́ lulẹ̀ lọ bá àwọn ẹni àtijọ́ tí wọ́n wà ninu ọ̀gbun. N óo mú kí o máa gbé ìsàlẹ̀ ilẹ̀ bí ìlú àwọn tí wọ́n ti ṣègbé nígbà àtijọ́, ati àwọn tí wọ́n ti lọ sinu ọ̀gbun; kí ẹnikẹ́ni má baà gbé inú rẹ mọ́, kí o má sì sí lórí ilẹ̀ alààyè mọ́. +N óo mú òpin tí ó bani lẹ́rù dé bá ọ, o kò sì ní sí mọ́; bí ẹnikẹ́ni tilẹ̀ ń wá ọ, ẹnìkan kò ní rí ọ mọ́ títí lae. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +“Nítorí náà, mo lòdì sí ọ, ìwọ Tire, n óo sì kó ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè wá gbógun tì ọ́, bíi ríru omi òkun. +Wọn óo wó odi Tire; wọn óo wó ilé-ìṣọ́ tí ó wà ninu rẹ̀ palẹ̀. N óo ha erùpẹ̀ inú rẹ̀ kúrò, n óo sì sọ ọ́ di àpáta lásán. +Yóo di ibi tí wọn óo máa sá àwọ̀n sí láàrin òkun, nítorí èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀; yóo sì di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. +Ogun yóo kó àwọn ìlú kéékèèké tí ó wà ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! N óo mú Nebukadinesari, ọba ńlá Babiloni wá, láti ìhà àríwá, yóo wá gbógun ti Tire. Nebukadinesari, ọba àwọn ọba óo wá, pẹlu ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun. +Yóo fi idà pa àwọn ará ìlú kéékèèké tí ó wà ní agbègbè tí ó yí ọ ká. Wọn óo mọ òkítì sí ara odi rẹ, wọn yóo ru erùpẹ̀ jọ, wọn óo fi la ọ̀nà lẹ́yìn odi rẹ, wọn óo sì fi asà borí nígbà tí wọ́n bá ń gun orí odi rẹ bọ̀. +Wọn óo fi ìtì igi wó odi rẹ, wọn óo sì fi àáké wó ilé-ìṣọ́ rẹ lulẹ̀. +Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Tire. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Àwọn ará Pasia ati àwọn ará Ludi ati àwọn ará Puti wà láàrin àwọn ọmọ ogun rẹ bí akọni. Wọ́n gbé asà ati àṣíborí wọn kọ́ sinu rẹ, wọ́n jẹ́ kí o gba ògo. +Àwọn ará Arifadi ati Heleki wà lórí odi rẹ yíká, àwọn ará Gamadi sì wà ninu àwọn ilé-ìṣọ́ rẹ. Wọ́n gbé asà wọn kọ́ káàkiri ara ògiri rẹ, àwọn ni wọ́n mú kí ẹwà rẹ pé. +“Àwọn ará Taṣiṣi ń bá ọ rajà nítorí ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ: fadaka, irin, páànù ati òjé ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ. +Àwọn ará Jafani, Tubali, ati Meṣeki ń bá ọ ṣòwò; wọ́n ń kó ẹrú ati ohun èlò idẹ wá fún ọ, wọn fi ń gba àwọn nǹkan tí ò ń tà. +Àwọn ará Beti Togama a máa kó ẹṣin, ati ẹṣin ogun, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà. +Àwọn ará Didani ń bá ọ ṣòwò, ọpọlọpọ etíkun ni ẹ tí ń tajà, wọ́n ń fi eyín erin ati igi Ẹboni ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ. +Àwọn ará Edomu bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà tí ò ń tà. Òkúta emeradi, aṣọ àlàárì, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́ tẹ́ẹ́rẹ́, iyùn ati òkúta agate ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ. +Juda ati ilé Israẹli bá ọ ṣòwò: wọ́n ń kó ọkà, èso olifi, àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́, oyin, òróró ati òrí wá láti fi ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà. +Àwọn ará Damasku bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà ati àwọn nǹkan olówó iyebíye tí ò ń tà, wọ́n mú ọtí waini ati irun aguntan funfun wá láti Heliboni. +Àwọn ará Fedani ati Jafani láti Usali a máa wá fi ọtí waini pààrọ̀ ohun tí ò ń tà; wọn a kó àwọn nǹkan èlò irin wá, ati igi kasia. +“Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nípa ìlú Tire. +Àwọn ará Dedani náà ń bá ọ ṣòwò, wọ́n ń kó aṣọ gàárì tí wọ́n fi ń gun ẹṣin wá. +Àwọn ará Arabia ati àwọn olóyè Kedari ni àwọn oníbàárà rẹ pataki, wọn a máa ra ọ̀dọ́ aguntan, àgbò, ati ewúrẹ́ lọ́wọ́ rẹ. +Àwọn oníṣòwò Ṣeba ati ti Raama náà a máa bá ọ ra ọjà, oríṣìíríṣìí turari olóòórùn dídùn ati òkúta olówó iyebíye ati wúrà ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́wọ́ rẹ. +Àwọn ará Harani, Kane, Edẹni, Aṣuri ati Kilimadi ń bá ọ ṣòwò. +Wọ́n ń kó ojúlówó ẹ̀wù aṣọ aláwọ̀ aró wá tà fún ọ, ati aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, ati ẹni tí ó ní oríṣìíríṣìí àwọ̀, tí wọ́n fi ìko hun. +Àwọn ọkọ̀ Taṣiṣi ní ń bá ọ ru ọjà rẹ lọ ta.Ọjà kún inú rẹ,ẹrù rìn ọ́ mọ́lẹ̀ láàrin omi òkun. +Àwọn tí ń wà ọ́ ti tì ọ́ sí ààrin agbami òkun.Atẹ́gùn ńlá ti dà ọ́ nù láàrin agbami òkun. +Gbogbo ọrọ̀ rẹ, ati gbogbo ọjà olówó iyebíye rẹ,àwọn tí ń tu ọkọ̀ rẹ ati àwọn tí ń darí rẹ;àwọn tí ń fi ọ̀dà dí ihò ara ọkọ̀ rẹati àwọn tí ń bá ọ ṣòwò.Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ ati àwọn èrò tí ó wà ninu rẹ,ni yóo rì sí ààrin gbùngbùn òkun, ní ọjọ́ ìparun rẹ. +Gbogbo èbúté yóo mì tìtìnígbà tí àwọn tí wọn ń tọ́ ọkọ̀ rẹ bá kígbe. +Gbogbo àwọn atukọ̀ ni yóo jáde kúrò ninu ọkọ̀.Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu ọkọ̀ati àwọn tí ń darí ọkọ̀yóo dúró ní èbúté. +Sọ fún ìlú Tire tí ó wà ní etí òkun, tí ń bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ṣòwò. Sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní:Tire, ìwọ tí ò ń sọ pé,o dára tóbẹ́ẹ̀, tí ẹwà rẹ kò kù síbìkan! +Wọn óo gbé ohùn sókè sí ọ,wọn óo sun ẹkún kíkan kíkan.Wọn óo da erùpẹ̀ sórí wọn,wọn óo yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú. +Wọn óo fá irun orí wọn nítorí rẹ,wọn óo sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìdí,wọn óo sì fi ìbànújẹ́ ọkàn sọkún nítorí rẹ,inú wọn yóo sì bàjẹ́. +Bí wọ́n bá ti ń sọkún,wọn óo máa kọ orin arò nípa rẹ báyìí pé:‘Ìlú wo ló tíì parun bíi Tire, láàrin òkun? +Nígbà tí àwọn ọjà rẹ bá dé láti òkè òkun,ò ń tẹ́ ọpọlọpọ eniyan lọ́rùn.Ò ń fi ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ ati ọjà rẹsọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀. +Wàyí ò, omi òkun ti fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́,o ti rì sí ìsàlẹ̀ òkun.’Gbogbo àwọn ọjà rẹati àwọn tí ń wa ọkọ̀ rẹ ti rì pẹlu rẹ. +“Ẹnu ya gbogbo àwọn tí ń gbé etí òkun nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ. Àwọn ọba wọn ń gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹ̀rù sì hàn ní ojú wọn. +Àwọn oníṣòwò orílẹ̀-èdè ayé ń pòṣé lé ọ lórí. Òpin burúkú dé bá ọ, o kò ní sí mọ́ títí lae.” +Agbami òkun ni bodè rẹ.Àwọn tí wọ́n kọ́ ọ fi ẹwà jíǹkí rẹ. +Igi firi láti Seniri ni wọ́n fi ṣe gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ.Igi kedari láti Lẹbanoni ni wọ́n sì fi ṣe òpó ọkọ̀ rẹ. +Igi oaku láti Baṣani ni wọ́n fi ṣe ajẹ̀ rẹ̀Igi sipirẹsi láti erékùṣù Kipru ni wọ́n fi ṣe ilé rẹ.Wọ́n sì fi eyín erin bo inú rẹ̀. +Aṣọ ọ̀gbọ̀ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára láti ilẹ̀ Ijipti,ni wọ́n fi ṣe ìgbòkun rẹtí ó dàbí àsíá ọkọ̀ rẹ.Aṣọ aláró ati aṣọ àlàárì láti etíkun Eliṣani wọ́n fi ṣe ìbòrí rẹ. +Àwọn ará Sidoni ati Arifadi ni atukọ̀ rẹ.Àwọn ọlọ́gbọ́n láti ilẹ̀ Ṣemeri wà lọ́dọ̀ rẹ,àwọn ni wọ́n ń darí ọkọ̀ ojú omi rẹ. +Àwọn àgbààgbà Gebali ati àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n oníṣẹ́ ọwọ́ wà lọ́dọ̀ rẹ,àwọn ni wọ́n ń fi ọ̀dà dí ọkọ̀ rẹkí omi má baà wọnú rẹ̀.Gbogbo ọkọ̀ ojú omi ati àwọn tí ń tù wọ́nwà lọ́dọ̀ rẹ, wọ́n ń bá ọ ra ọjà. +Orin Arò fún Ìlú Tire. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +Ikú aláìkọlà ni o óo kú lọ́wọ́ àwọn àjèjì, nítorí èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nítorí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ọba Tire. Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘O ti jẹ́ àpẹẹrẹ ìwà pípé, o kún fún ọgbọ́n, o sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí o kò ní àbùkù kankan. +O wà ninu Edẹni, ọgbà Ọlọrun. Gbogbo òkúta olówó iyebíye ni wọ́n fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn òkúta bíi: kaneliani, topasi, ati jasiperi; kirisolite, bẹrili, ati onikisi; safire, kabọnku ati emeradi. A gbé ọ ka inú àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí a ṣe fún ọ ní ọjọ́ tí a dá ọ. +Mo fi kerubu tí a fi àmì òróró yàn tì ọ́. O wà lórí òkè mímọ́ èmi Ọlọrun, o sì ń rìn láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin. +O péye ninu gbogbo ọ̀nà rẹ, láti ọjọ́ tí wọ́n ti dá ọ títí di ìgbà tí a rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ. +Ninu ọpọlọpọ òwò tí ó ń ṣe, o bẹ̀rẹ̀ sí hu ìwà jàgídíjàgan, o sì dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà mo lé ọ jáde bí ohun ìríra kúrò lórí òkè Ọlọrun. Kerubu tí ń ṣọ́ ọ sì lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin. +Ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga nítorí pé o lẹ́wà, o ba ọgbọ́n rẹ jẹ́ nítorí ògo rẹ. Mo bì ọ́ lulẹ̀, mo sọ ọ́ di ìran wíwò fún àwọn ọba. +O ti fi ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí o dá nítorí ìwà aiṣootọ ninu òwò rẹ, ba ibi mímọ́ mi jẹ́. Nítorí náà, mo jẹ́ kí iná ṣẹ́ ní ààrin rẹ; ó sì jó ọ run; mo sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀ ayé lójú gbogbo àwọn tí ń wò ọ́. +Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́ láàrin àwọn eniyan láyé ni ó yà lẹ́nu nígbà tí wọ́n rí ọ. Òpin burúkú ti dé bá ọ, o kò sì ní sí mọ́ títí ayé.’ ” +“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún ọba Tire pé OLUWA ní, ‘Nítorí pé ìgbéraga kún ọkàn rẹ, o sì ti sọ ara rẹ di oriṣa, o sọ pé o jókòó ní ibùjókòó àwọn oriṣa láàrin òkun; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan ni ọ́, o kì í ṣe oriṣa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń rò pé o gbọ́n bí àwọn oriṣa, +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú rẹ sí Sidoni, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé +OLUWA Ọlọrun ní, ‘Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni. N óo sì fi ògo mi hàn láàrin rẹ. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé inú rẹ; tí mo sì fi ìwà mímọ́ mi hàn wọ́n. +Nítorí n óo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá ọ jà n óo sì jẹ́ kí àgbàrá ẹ̀jẹ̀ máa ṣàn ní ìgboro rẹ. Àwọn tí wọ́n yí ọ ká yóo gbógun tì ọ́, wọn óo sì fi idà pa ọpọlọpọ eniyan ninu rẹ,’ nígbà náà o óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ti ilé Israẹli, kò ní sí ọ̀tá tí yóo máa ṣe ẹ̀gún gún wọn mọ́, láàrin gbogbo àwọn tí wọ́n yí wọn ká tí wọ́n sì ń kẹ́gàn wọn. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA. +“Nígbà tí mo bá kó àwọn ará ilé Israẹli jọ kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, tí mo sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrin wọn, lójú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, wọn óo máa gbé ilẹ̀ tiwọn, ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu iranṣẹ mi. +Wọn óo máa gbé ibẹ̀ láìbẹ̀rù; wọn óo kọ́ ilé, wọn óo sì ṣe ọgbà àjàrà, wọn óo máa gbé láìbẹ̀rù nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n yí wọn ká, tí wọ́n sì ti kẹ́gàn wọn. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.” +nítòótọ́, o gbọ́n ju Daniẹli lọ, kò sì sí ohun àṣírí kan tí ó ṣú ọ lójú. +Nípa ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ, o ti kó ọpọlọpọ ọrọ̀ jọ fún ara rẹ, o sì kó wúrà ati fadaka jọ sinu ilé ìṣúra rẹ. +O ti ní àníkún ọrọ̀ nítorí ọgbọ́n rẹ ninu òwò ṣíṣe, ìgbéraga sì ti kún ọkàn rẹ nítorí ọrọ̀ rẹ.’ +“Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Nítorí pé o ka ara rẹ kún ọlọ́gbọ́n bí àwọn oriṣa, +n óo kó àwọn àjèjì wá bá ọ; àwọn tí wọ́n burú jù ninu àwọn orílẹ̀-èdè, wọn óo sì gbógun tì ọ́, wọ́n yóo sì ba ẹwà ati ògo rẹ jẹ́, pẹlu ọgbọ́n rẹ. +Wọn óo tì ọ́ sinu ọ̀gbun; o óo sì kú ikú ogun láàrin omi òkun. +Ṣé o óo lè sọ pé oriṣa kan ni ọ́ lójú àwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa ọ́? Nígbà tí wọ́n bá ń ṣá ọ lọ́gbẹ́, ṣé eniyan ni o óo wá pe ara rẹ àbí oriṣa. +Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Ọba Tire. +Ní ọjọ́ kejila oṣù kẹwaa ọdún kẹwaa, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; +nítorí náà, mo lòdì sí ìwọ ati àwọn odò rẹ, n óo sì sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro ati aṣálẹ̀ patapata láti Migidoli dé Siene, títí dé ààlà Etiopia. +Eniyan tabi ẹranko kò ní gba ibẹ̀ kọjá, ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ fún ogoji ọdún. +N óo sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro patapata, n óo jẹ́ kí àwọn ìlú rẹ̀ di ahoro fún ogoji ọdún. N óo fọ́n àwọn ará Ijipti káàkiri gbogbo ayé, n óo sì tú wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Lẹ́yìn ogoji ọdún, n óo kó àwọn ará Ijipti jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo bá fọ́n wọn ká sí. +N óo dá ire wọn pada, n óo kó wọn pada sí ilẹ̀ Patirosi, níbi tí a bí wọn sí. Wọn óo sì wà níbẹ̀ bí ìjọba tí kò lágbára. +Òun ni yóo rẹlẹ̀ jù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, kò ní lè gbé ara rẹ̀ ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́. N óo sọ wọ́n di kékeré tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè jọba lórí orílẹ̀-èdè kankan mọ́. +Ijipti kò ní tó gbójú lé fún àwọn ọmọ Israẹli mọ́. Ijipti yóo máa rán wọn létí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, pé wọ́n ti wá bèèrè ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn ará Ijipti tẹ́lẹ̀ rí. Wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.” +Ní ọjọ́ kinni, oṣù kinni, ọdún kẹtadinlọgbọn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ìwọ ọmọ eniyan, Nebukadinesari ọba Babiloni mú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Tire kíkankíkan. Wọ́n ru ẹrù títí orí gbogbo wọn pá, èjìká gbogbo wọn sì di egbò. Sibẹ òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò rí èrè kankan gbà ninu gbogbo wahala tí wọ́n ṣe ní Tire. +Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun óo fi ilẹ̀ Ijipti lé Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́. Yóo kó àwọn eniyan rẹ̀ lọ, yóo sì fi ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ṣe ìkógun, èyí ni yóo jẹ́ èrè fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀. +Ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú rẹ sí Farao ọba Ijipti, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa òun ati gbogbo àwọn ará Ijipti pé, +Mo ti fún un ní ilẹ̀ Ijipti gẹ́gẹ́ bí èrè gbogbo wahala rẹ̀, nítorí pé èmi ni ó ṣiṣẹ́ fún. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Ní ọjọ́ náà, n óo gbé alágbára kan dìde ní Israẹli, n óo mú kí ìwọ Isikiẹli ó sọ̀rọ̀ láàrin wọn. Nígbà náà, wọn yóo mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +OLUWA Ọlọrun ní: Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Farao, ọba Ijipti, Ìwọ diragoni ńlá tí o wà láàrin odò rẹ; tí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili mi; ara mi ni mo dá a fún.’ +N óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu, n óo sì jẹ́ kí àwọn ẹja inú odò Naili so mọ́ ìpẹ́ rẹ; n óo sì fà ọ́ jáde kúrò ninu odò Naili rẹ pẹlu gbogbo àwọn ẹja inú odò rẹ tí wọn óo so mọ́ ọ lára. +N óo gbé ọ jù sinu aṣálẹ̀, ìwọ ati gbogbo ẹja inú odò Naili rẹ. Ẹ ó bọ́ lulẹ̀ ninu pápá tí ó tẹ́jú. Ẹnìkan kò sì ní kó òkú yín jọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin yín. Mo ti fi yín ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ. +Gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Ijipti yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. “Nítorí pé ẹ fi ara yín ṣe ọ̀pá tí àwọn ọmọ Israẹli gbára lé; ṣugbọn ọ̀pá tí kò gbani dúró ni yín. +Nígbà tí wọ́n gba yín mú, dídá ni ẹ dá mọ́ wọn lọ́wọ́, tí ẹ ya wọ́n léjìká pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Nígbà tí wọ́n gbára le yín, ẹ dá ẹ sì jẹ́ kí wọ́n dá lẹ́yìn.” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Wò ó, n óo fi ogun jà yín, n óo sì pa yín run, ati eniyan ati ẹranko. +Ilẹ̀ Ijipti yóo di ahoro, yóo sì di aṣálẹ̀. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.“Nítorí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili, ara mi ni mo dá a fún,’ +Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Ijipti. +Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ Eniyan, jẹ ohun tí a fún ọ; jẹ ìwé tí a ká yìí, kí o sì lọ bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.” +Ó tún sọ fún mi, pé, “Ọmọ eniyan, fi etí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí n óo bá ọ sọ, kí o sì fi wọ́n sọ́kàn. +Lọ bá àwọn eniyan rẹ tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, kí o sọ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ fún wọn; wọn ìbáà gbọ́, wọn ìbáà má sì gbọ́.” +Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, mo sì gbọ́ ìró kan lẹ́yìn mi tí ó dàbí ariwo ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá, ó ní, “Ẹ fi ìyìn fún ìfarahàn ògo OLUWA ní ibùgbé rẹ̀.” +Ìró ìyẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà ni mò ń gbọ́ tí wọn ń kan ara wọn, ati ìró àgbá wọn; ó dàbí ìró ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá. +Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, ó sì gbé mi lọ. Tìbínú-tìbínú ni mo sì fi ń lọ. Ẹ̀mí OLUWA ni ó gbé mi lọ pẹlu agbára. +Mo bá dé Teli Abibu lọ́dọ̀ àwọn ìgbèkùn tí wọn ń gbé ẹ̀bá odò Kebari. Ọjọ́ meje ni mo fi wà pẹlu wọn, tí mo jókòó tì wọ́n, tí mò ń wò wọ́n tìyanu-tìyanu. +Lẹ́yìn ọjọ́ keje, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +“Ọmọ eniyan, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli. Nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ohunkohun lẹ́nu mi, o gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn. +Bí mo bá sọ fún eniyan burúkú pé dájúd��jú yóo kú, ṣugbọn tí o kò kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi tí ó ń rìn kí ó lè yè, eniyan burúkú náà yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣugbọn lọ́wọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. +Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú, tí kò bá yipada kúrò ninu iṣẹ́ burúkú tí ó ń ṣe, tabi ọ̀nà ibi tí ó ń tọ̀; yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ óo gba ara rẹ là. +Mo bá la ẹnu, ó sì fún mi ní ìwé náà jẹ. +“Bẹ́ẹ̀ náà sì ni bí olódodo bá yipada kúrò ninu òdodo rẹ̀, tí ó bá dẹ́ṣẹ̀, tí mo sì gbé ohun ìkọsẹ̀ kan siwaju rẹ̀, yóo kú, nítorí pé o kò kìlọ̀ fún un, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a kò sì ní ranti iṣẹ́ òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe; ṣugbọn n óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ. +Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún olódodo náà pé kí ó má dẹ́ṣẹ̀, tí kò sì dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú yóo yè, nítorí pé ó gbọ́ ìkìlọ̀; ìwọ náà yóo sì gba ẹ̀mí ara rẹ là.” +Ẹ̀mí OLUWA sì wà lára mi, ó sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí àfonífojì, níbẹ̀ ni n óo ti bá ọ sọ̀rọ̀.” +Mo bá dìde, mo jáde lọ sí àfonífojì. Mo rí ìfarahàn ògo OLUWA níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti rí i lẹ́bàá odò Kebari, mo bá dojúbolẹ̀. +Ṣugbọn ẹ̀mí Ọlọrun kó sí mi ninu, ó sì gbé mi nàró; ó bá mi sọ̀rọ̀, ó sọ fún mi pé, “Lọ ti ara rẹ mọ́ ilé rẹ. +Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! A óo na okùn lé ọ lórí, a óo sì fi okùn náà dè ọ́, kí o má baà lè jáde sí ààrin àwọn eniyan. +N óo mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ ọ lẹ́nu kí o sì ya odi, kí o má baà lè kìlọ̀ fún wọn, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn. +Ṣugbọn bí mo bá bá ọ sọ̀rọ̀ tán, n óo là ọ́ lóhùn, o óo sì sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun bá sọ fún wọn. Ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó gbọ́, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó má gbọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn.” +Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, jẹ ìwé tí a ká, tí mo fún ọ yìí, kí o sì yó.” Mo bá jẹ ẹ́, ó sì dùn bí oyin lẹ́nu mi. +Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, lọ bá àwọn ọmọ Israẹli kí o sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn. +Kì í sá ṣe àwọn tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí ó ṣòro gbọ́, ni mo rán ọ sí, àwọn ọmọ ilé Israẹli ni. +N kò rán ọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí yóo ṣòro fún ọ láti gbọ́. Dájúdájú, bí ó bá jẹ́ irú wọn ni mo rán ọ sí, wọn ìbá gbọ́ tìrẹ. +Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò ní gbọ́ tìrẹ, nítorí pé wọn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Olóríkunkun ati ọlọ́kàn líle ni gbogbo wọn. +Mo ti mú kí ojú rẹ le sí tiwọn. +Bí òkúta adamanti ṣe le ju òkúta akọ lọ ni mo ṣe mú kí orí rẹ le ju orí wọn lọ. Má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí ojú wọn já ọ láyà, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.” +OLUWA Yan Isikiẹli Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣọ́. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ti ọwọ́ Nebukadinesari, ọba Babiloni, fi òpin sí ọrọ̀ Ijipti. +Òun ati àwọn eniyan rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè oníjàgídíjàgan jùlọ ni, yóo wá pa ilẹ̀ Ijipti run, wọn yóo yọ idà ti Ijipti, ọpọlọpọ yóo sì kú ní ilẹ̀ náà. +N óo mú kí odò Naili gbẹ, n óo ta ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan burúkú; n óo sì jẹ́ kí àwọn àjèjì sọ ilẹ̀ náà ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ di ahoro. Èmi OLUWA ní mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA Ọlọrun ní, “N óo fọ́ àwọn ère tí ó wà ní Memfisi, n óo sì pa wọ́n run. Kò ní sí ọba ní ilẹ̀ Ijipti mọ́, n óo jẹ́ kí ìbẹ̀rù dé bá ilẹ̀ Ijipti. +N óo sọ Patirosi di ahoro, n óo sì dáná sun Soani, n óo sì ṣe ìdájọ́ fún ìlú Tebesi. +N óo bínú sí Pelusiumu, ibi ààbò Ijipti, n óo sì pa ogunlọ́gọ̀ àwọn tí ń gbé Tebesi. +N óo dáná sun Ijipti, Pelusiumu yóo sì wà ninu ìrora ńlá. +N óo fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin Oni ati ti Pibeseti; a óo sì kó àwọn obinrin wọn lọ sí ìgbèkùn. +Ojú ọjọ́ yóo ṣókùnkùn ní Tehafinehesi nígbà tí mo bá ṣẹ́ ọ̀pá ìjọba Ijipti, agbára tí ó ń gbéraga sí yóo sì dópin. Ìkùukùu óo bò ó mọ́lẹ̀; wọn óo sì kó àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn. +Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe ṣe ìdájọ́ Ijipti, wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé, OLUWA Ọlọrun ní, +Ní ọjọ́ keje, oṣù kinni ọdún kọkanla, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ìwọ ọmọ eniyan, mo ti ṣẹ́ Farao, ọba Ijipti, lápá, a kò sì tíì dí i, kí ọgbẹ́ rẹ̀ fi san, kí ó sì fi lágbára láti gbá idà mú. +Nítorí náà, mo lòdì sí Farao, ọba Ijipti. Èmi OLUWA Ọlọrun ní mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo ṣẹ́ ẹ ní apá mejeeji: ati èyí tó ṣì lágbára, ati èyí tí ó ti ṣẹ́ tẹ́lẹ̀; n óo sì gbọn idà bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. +N óo fọ́n àwọn ará Ijipti ká orílẹ̀-èdè ayé, n óo sì tú wọn káàkiri gbogbo ilẹ̀ ayé. +N óo fún ọba Babiloni lágbára, n óo sì fi idà mi lé e lọ́wọ́; ṣugbọn n óo ṣẹ́ Farao lápá; yóo máa kérora níwájú rẹ̀ bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́ tí ó ń kú lọ. +N óo fún ọba Babiloni lágbára, ṣugbọn ọwọ́ Farao yóo rọ. Wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA. Nígbà tí mo bá fi idà mi lé ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo fa idà náà yọ yóo gbógun ti ilẹ̀ Ijipti. +N óo fọ́n àwọn ará Ijipti ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, n óo sì tú wọn káàkiri gbogbo ilẹ̀ ayé. Wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +‘Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí ọjọ́ burúkú tí ń bọ̀,nítorí ọjọ́ náà súnmọ́lé,ọjọ́ OLUWA ti dé tán,yóo jẹ́ ọjọ́ ìṣúduduati ìparun fún àwọn orílẹ̀-èdè. +Ogun yóo jà ní Ijipti,ìrora yóo sì bá Etiopia.Nígbà tí ọpọlọpọ òkú bá sùn ní Ijipti,tí a kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ,tí a sì wó ìpìlẹ̀ rẹ̀ lulẹ̀. +“ ‘Àwọn ará Etiopia, ati Puti, ati Ludi, ati gbogbo ilẹ̀ Arabia ati Libia, ati gbogbo àwọn eniyan wa tí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀, ni ogun yóo pa.’ ” +OLUWA ní, “Àwọn tí ń ran Ijipti lọ́wọ́ yóo ṣubú,ìgbéraga rẹ̀ yóo sì wálẹ̀;láti Migidoli títí dé Siene,wọn ó kú ikú ogun láàrin ìlú.Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Ijipti óo di ahoro patapata àwọn ìlú rẹ̀ yóo wà lára àwọn ìlú tí yóo tú patapata. +Wọn yóo mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá dáná sun Ijipti, tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá ṣubú. +“Nígbà tó bá tó àkókò, n óo rán àwọn ikọ̀ ninu ọkọ̀ ojú omi, wọn ó lọ dẹ́rù ba àwọn ará Etiopia tí wọn ń gbé láìfura. Wahala yóo dé bá àwọn ará Etiopia ní ọjọ́ ìparun Ijipti. Wò ó, ìparun náà ti dé tán.” +OLUWA Yóo Jẹ Ijipti Níyà. +Ní ọjọ́ kinni, oṣù kẹta, ọdún kọkanla tí a ti wà ní ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Nítorí pé ó ga sókè fíofío, góńgó orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu lójú ọ̀run, ọkàn rẹ̀ sì kún fún ìgbéraga nítorí gíga rẹ̀. +N óo fi lé ẹni tí ó lágbára jù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, yóo sì ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo lé e jáde. +Àwọn àjèjì láti inú orílẹ̀-èdè, tí ó burú jùlọ, yóo gé e lulẹ̀, wọn yóo sì fi í sílẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo bọ́ sílẹ̀ lórí àwọn òkè ati ní àwọn àfonífojì, igi rẹ̀ yóo sì wà nílẹ̀ káàkiri ní gbogbo ipadò ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo kúrò lábẹ́ òjìji rẹ̀, wọn yóo sì fi sílẹ̀. +Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run yóo kọ́lé sórí ìtì igi rẹ̀ tí ó wó lulẹ̀. Gbogbo ẹranko inú igbó yóo tẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ mọ́lẹ̀. +Gbogbo èyí yóo ṣẹlẹ̀ kí igi mìíràn tí ó bá wà lẹ́bàá omi náà má baà ga fíofío mọ́, tabi kí orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu ní ojú ọ̀run. Kò sì ní sí igi tí ń fa omi, tí yóo ga tó ọ; nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kú, tí wọn óo sì lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun ilẹ̀ bí àwọn alààyè eniyan tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú.” +OLUWA Ọlọrun ní: “Nígbà tí ó bá wọ isà òkú ọ̀gbun ilẹ̀ pàápàá, n óo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, n óo sé àwọn odò n óo sì ti orísun omi ìsàlẹ̀ ilẹ̀ nítorí rẹ̀, òkùnkùn óo bo Lẹbanoni, gbogbo igi inú igbó yóo gbẹ nítorí rẹ̀. +Ìró wíwó rẹ̀ yóo mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì. Nígbà tí mo bá wó o lulẹ̀ tí mo bá sọ ọ́ sinu isà òkú pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú; gbogbo àwọn igi Edẹni, ati àwọn igi tí wọ́n dára jù ní Lẹbanoni, gbogbo àwọn igi tí ń rí omi mu lábẹ́ ilẹ̀ ni ara yóo tù. +Àwọn náà yóo lọ sí ipò òkú pẹlu rẹ̀, sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fi idà pa; àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń gbé abẹ́ òjìji rẹ̀ yóo sì parun. +“Ògo ati títóbi ta ni a lè fi wé tìrẹ láàrin àwọn igi tí ó wà ní Edẹni? Ṣugbọn a óo gé ọ lulẹ̀ pẹlu àwọn igi ọgbà Edẹni, a óo sì wọ́ ọ sọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. O óo wà nílẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà, pẹlu àwọn tí a fi idà pa. Farao ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ni mò ń sọ nípa wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún Farao, ọba Ijipti, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé,Ta ni ó lágbára tó ọ? +Wò ó! Mo fi ọ́ wé igi kedari Lẹbanoni,àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lẹ́wà,wọ́n sì ní ìbòòji ó ga fíofío,orí rẹ̀ sì kan ìkùukùu lójú ọ̀run. +Omi mú kí ó dàgbà,ibú omi sì mú kí ó ga.Ó ń mú kí àwọn odò rẹ̀ ṣàn yí ibi tí a gbìn ín sí ká.Ó ń mú kí odò rẹ̀ ṣàn lọ síbi gbogbo igi igbó. +Nítorí náà, ó ga sókè fíofío, ju gbogbo igi inú igbó lọ.Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tóbi, wọ́n sì gùn,nítorí ọpọlọpọ omi tí ó ń rí. +Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, pa ìtẹ́ sára àwọn ẹ̀ka rẹ̀.Lábẹ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹranko inú igbó ń bímọ sí.Gbogbo orílẹ̀-èdè ńláńlá sì fi ìbòòji abẹ́ rẹ̀ ṣe ibùgbé. +Ó tóbi, ó lọ́lá ẹ̀ka rẹ̀ sì lẹ́wànítorí pé gbòǹgbò rẹ̀ wọ ilẹ̀ lọ,ó sì kan ọpọlọpọ omi nísàlẹ̀ ilẹ̀. +Igi kedari tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun kò lè farawé e.Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ka igi firi kò sì tó ẹ̀ka rẹ̀.Ẹ̀ka igi kankan kò dàbí ẹ̀ka rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò sí igikígi ninu ọgbà Ọlọrun tí ó lẹ́wà bíi rẹ̀. +Mo dá a ní arẹwà, pẹlu ẹ̀ka tí ó pọ̀.Gbogbo igi ọgbà Edẹni,tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun sì ń jowú rẹ̀. +A Fi Ijipti Wé Igi Kedari. +Ní ọjọ́ kinni oṣù kejila, ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀. +N óo jẹ́ kí ẹnu ya ọpọlọpọ eniyan nítorí yín, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì wárìrì nítorí tiyín, nígbà tí mo bá ń fi idà mi lójú wọn, olukuluku wọn óo máa wárìrì nígbàkúùgbà nítorí ẹ̀mí ara rẹ̀, ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.” +OLUWA Ọlọrun sọ fún ọba Ijipti pé, “Ọba Babiloni yóo fi idà pa yín. +N óo wá àwọn alágbára, àwọn tí wọ́n burú jùlọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo jẹ́ kí gbogbo wọn fi idà pa ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ. Wọn yóo sọ ìgbéraga Ijipti di asán, ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ yóo sì parun. +N óo pa gbogbo ẹran ọ̀sìn Ijipti tí ó wà ní etí odò run. Àwọn eniyan kò sì ní fi ẹsẹ̀ da omi rú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko kò ní fi pátákò da odò rú mọ́. +N óo wá jẹ́ kí odò wọn ó tòrò, kí wọn máa ṣàn bí òróró. Èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro, tí mo bá pa gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ run; tí mo bá pa gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ run, wọn yóo mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA. +Àwọn eniyan yóo máa kọ ọ̀rọ̀ yìí ní orin arò; àwọn ọmọbinrin ní àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo máa kọ ọ́. Wọn óo máa kọ ọ́ nípa Ijipti ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀. Èmi, OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kinni, ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn, +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan Ijipti, rán àwọn ati àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́lá yòókù lọ sinu isà òkú, sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti fi ilẹ̀ bora. +Sọ fún wọn pé,‘Ta ni ó lẹ́wà jùlọ?Sùn kalẹ̀, kí á sì tẹ́ ọ sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà.’ +Ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, gbé ohùn sókè kí o kọ orin arò nípa Farao, ọba Ijipti. Wí fún un pé ó ka ara rẹ̀ kún kinniun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Ṣugbọn ó dàbí diragoni ninu omi. Ó ń jáde tagbára tagbára láti inú odò, ó ń fẹsẹ̀ da omi rú, ó sì ń dọ̀tí àwọn odò. +“Wọn yóo ṣubú láàrin àwọn tí wọ́n kú ikú ogun; ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ yóo ṣubú pẹlu rẹ̀. +Àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ akọni ati àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn yóo máa sọ nípa wọn ninu isà òkú pé, ‘Àwọn aláìkọlà tí a fi idà pa ti ṣubú, wọ́n ti wọlẹ̀, wọ́n sùn, wọn kò lè mira.’ +“Asiria náà wà níbẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ibojì àwọn tí wọ́n ti kú yí i ká. Gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun. +Ibojì rẹ̀ wà ní ìpẹ̀kun isà òkú. Ibojì àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì tò yí tirẹ̀ ká. Àwọn tí ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láyé, gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun. +“Elamu náà wà níbẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ibojì wọn yí ibojì rẹ̀ ká. Gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun. Wọ́n sì lọ sinu isà òkú ní àìkọlà abẹ́. Àwọn tí ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè, wọ́n fi ìtìjú wọlẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀, wọn lọ bá àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú. +Wọ́n tẹ́ ibùsùn fún Elamu láàrin àwọn tí wọ́n kú sójú ogun pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀. Ibojì wọn yí tirẹ̀ ká, gbogbo wọn ni a fi idà pa láìkọlà abẹ́. Wọ́n ń dẹ́rù ba àwọn eniyan nígbà tí wọ́n wà láàyè. Wọ́n fi ìtìjú wọlẹ̀ lọ, wọ́n lọ bá àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú. A kó gbogbo wọn pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n kú sójú ogun. +“Meṣeki ati Tubali wà níbẹ̀ pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan wọn. Ibojì wọn yí ibojì rẹ̀ ká, gbogbo wọn ni wọ́n kú lójú ogun ní aláìkọlà. Nítorí wọ́n ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè. +Wọn kò sin wọ́n bí àwọn alágbára tí wọ́n wà ní àtijọ́ tí wọ́n sin sí ibojì pẹlu ohun ìjà ogun wọn lára wọn: àwọn tí a gbé orí wọn lé idà wọn, wọ́n sì fi asà wọn bo egungun wọn mọ́lẹ̀; nítorí àwọn alágbára wọnyi dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè. +“Nítorí náà, a óo wó ọ mọ́lẹ̀, o óo sì sùn láàrin àwọn aláìkọlà pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. +“Edomu náà wà níbẹ̀ pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀. Bí wọ́n ti lágbára tó, wọ́n sùn pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Wọ́n sùn pẹlu àwọn aláìkọlà, pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú. +Sọ pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní n óo da àwọ̀n mi bò ó níṣojú ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan; wọn óo sì fi àwọ̀n mi wọ́ ọ sókè. +“Gbogbo àwọn olórí láti apá àríwá wà níbẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Sidoni, tí wọ́n fi ìtìjú wọlé lọ sí ipò òkú pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lo agbára wọn láti dẹ́rù bani, wọ́n sùn láìkọlà, pẹlu ìtìjú, pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Pẹlu àwọn tí wọ́n lọ sinu isà òkú. +“Nígbà tí Farao bá rí wọn, Tòun ti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a fi idà pa, yóo dá ara rẹ̀ lọ́kàn le, nítorí gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +“Mo mú kí Farao dẹ́rù ba àwọn eniyan nígbà tí ó wà láyé. Nítorí náà, a óo sin òun ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ sí ààrin àwọn aláìkọlà, láàrin àwọn tí wọ́n kú lójú ogun.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun wí. +N óo wọ́ ọ jù sórí ilẹ̀; inú pápá ni n óo sọ ọ́ sí, n óo jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run pa ìtẹ́ wọn lé e lórí. N óo sì jẹ́ kí àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé jẹ ẹran ara rẹ. +N óo sọ ẹran ara rẹ̀ káàkiri sí orí àwọn òkè. N óo sì fi òkú rẹ̀ kún àwọn àfonífojì. +N óo tú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà sórí ilẹ̀ ati sórí àwọn òkè, gbogbo ipadò yóo sì kún fún ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. +Nígbà tí mo bá pa á rẹ́, n óo bo ojú ọ̀run; n óo jẹ́ kí ìràwọ̀ ṣóòkùn n óo fi ìkùukùu bo oòrùn lójú, òṣùpá kò sì ní tan ìmọ́lẹ̀. +Gbogbo àwọn ìmọ́lẹ̀ tí ó ń tàn lójú ọ̀run ni n óo jẹ́ kí ó di òkùnkùn lórí rẹ̀, n óo jẹ́ kí òkùnkùn bo ilẹ̀ rẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“N óo jẹ́ kí ọkàn ọpọlọpọ eniyan dààmú nígbà tí mo bá ko yín ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ tí ẹ kò dé rí, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ayé. +A Fi Ọba Ijipti Wé Diragoni. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé mo gbọ́ ohun tí wọn ń sọ pé, ‘Àìdára wa ati ẹ̀ṣẹ̀ wa wà lórí wa, a sì ń joró nítorí wọn; báwo ni a óo ṣe yè?’ +Wí fún wọn pé èmi OLUWA ní, mo fi ara mi búra pé inú mi kò dùn sí ikú eniyan burúkú, ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì yè. Ẹ yipada! Ẹ yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú? +“Ìwọ ọmọ eniyan, wí fún àwọn eniyan rẹ pé, bí olódodo bá dẹ́ṣẹ̀ ìwà òdodo rẹ̀ kò ní gbà á là, bẹ́ẹ̀ sì ni bí eniyan burúkú bá yí ìwà rẹ̀ pada, kò ní kú nítorí ìwà burúkú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni bí olódodo bá dẹ́ṣẹ̀, kò ní yè nítorí òdodo rẹ̀. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo wí fún olódodo pé yóo yè, bí ó bá gbójú lé òdodo ara rẹ̀, tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, n kò ní ranti ọ̀kankan ninu ìwà òdodo rẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá. +Bí mo bá sì wí fún eniyan burúkú pé dandan ni pé kí ó kú, bí ó bá yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́, +bí ó bá dá nǹkan tí ẹni tí ó jẹ ẹ́ ní gbèsè fi ṣe ìdúró pada, tí ó sì dá gbogbo nǹkan tí ó jí pada, tí ó ń rìn ní ọ̀nà ìyè láì dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú yóo yè; kò ní kú. +N kò ní ranti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí o ti dá mọ́. Nítorí pé ó ti ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́, yóo yè. +“Sibẹsibẹ, àwọn eniyan rẹ ń wí pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́,’ bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀nà tiwọn gan-an ni kò tọ́. +Bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. +Bí eniyan burúkú bá sì yipada kúrò ninu ibi tí ó ń ṣe, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ́, yóo yè nítorí rere tí ó ṣe. +“Ìwọ ọmọ eniyan, bá àwọn eniyan rẹ sọ̀rọ̀. Wí fún wọn pé bí mo bá jẹ́ kí ogun jà ní ilẹ̀ kan, tí àwọn eniyan ibẹ̀ bá yan ọ̀kan ninu wọn, tí wọ́n fi ṣe olùṣọ́; +Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń wí pé, ‘ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ìwà olukuluku yín ni n óo fi dá a lẹ́jọ́.” +Ní ọjọ́ karun-un oṣù kẹwaa ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn, ẹnìkan tí ó sá àsálà kúrò ní Jerusalẹmu wá sọ́dọ̀ mi, ó ní, “Ogun ti kó Jerusalẹmu.” +Ẹ̀mí OLUWA ti bà lé mi ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ tí ẹni tí ó sá àsálà náà dé, OLUWA sì ti là mí lóhùn kí ọkunrin náà tó dé ọ̀dọ̀ mi ní àárọ̀ ọjọ́ keji; n kò sì yadi mọ́. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +“Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli tí ó ti di aṣálẹ̀ wọnyi, ń wí pé, ‘Ẹnìkan péré ni Abrahamu, bẹ́ẹ̀ ó sì gba ilẹ̀ yìí. Àwa pọ̀ ní tiwa, nítorí náà, a ti fi ilẹ̀ yìí fún wa, kí á gbà á ló kù.’ +“Nítorí náà, wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, Ẹ̀ ń jẹ ẹran pẹlu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀ ń bọ oriṣa, ẹ sì ń pa eniyan, ṣé ẹ rò pé ilẹ̀ náà yóo di tiyín? +Idà ni ó kù tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé; ẹ̀ ń ṣe ohun ìríra, ẹ̀ ń bá iyawo ara yín lòpọ̀, ẹ sì rò pé ẹ óo jogún ilẹ̀ yìí? +“Mo fi ara mi búra, ogun ni yóo pa àwọn tí ń gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo jẹ́ kí ẹranko burúkú pa àwọn tí wọ́n wà ninu pápá jẹ, àjàkálẹ̀ àrùn yóo sì pa àwọn tí wọ́n sápamọ́ sí ibi ààbò ati ninu ihò àpáta. +N óo sọ ilẹ̀ yìí di ahoro ati aṣálẹ̀. Agbára tí ó ń gbéraga sí yóo dópin. Àwọn òkè Israẹli yóo di ahoro tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní gba ibẹ̀ kọjá. +Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ náà di ahoro ati aṣálẹ̀, nítorí gbogbo ìwà ìríra tí wọ́n ti hù. +bí ó bá rí ogun tí ń bọ̀ wá sí ilẹ̀ náà, tí ó bá fọn fèrè tí ó fi kìlọ̀ fún àwọn eniyan, +“Ní tìrẹ, ìwọ ọmọ eniyan, àwọn eniyan rẹ tí ń sọ̀rọ̀ rẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri ati lẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé wọn, wọ́n ń wí fún ara wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ gbọ́ ohun tí OLUWA wí.’ +Wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ bí àwọn eniyan tií wá, wọ́n sì ń jókòó níwájú rẹ bí eniyan mi. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é; nítorí pé ẹnu lásán ni wọ́n fi ń sọ pé wọ́n ní ìfẹ́ pupọ, ṣugbọn níbi èrè tí wọn ó jẹ ni ọkàn wọn wà. +Lójú wọn, o dàbí olóhùn iyọ̀ tí ń kọrin ìfẹ́, tí ó sì mọ ohun èlò orin lò dáradára. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é. +Ṣugbọn nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ, (bẹ́ẹ̀ yóo sì ṣẹ), wọn óo wá mọ̀ pé wolii kan wà láàrin wọn.” +bí ẹnìkan bá gbọ́ ìró fèrè náà, ṣugbọn tí kò bá bìkítà fún ogun àgbọ́-tẹ́lẹ̀ yìí, bí ogun bá pa á orí ara rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà. +Ó gbọ́ ìró fèrè ṣugbọn kò bìkítà, nítorí náà orí ara rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà. Bí ó bá gbọ́ ìkìlọ̀ ni, kì bá gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. +Ṣugbọn bí olùṣọ́ bá rí i pé ogun ń bọ̀, tí kò bá fọn fèrè kí ó kìlọ̀ fún àwọn eniyan; bí ogun bá pa ẹnikẹ́ni ninu wọn, ẹni tí ogun pa yóo kú ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn èmi OLUWA óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ olùṣọ́ náà. +“Ọmọ eniyan, ìwọ ni mo yàn ní olùṣọ́ fún ilé Israẹli; nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́nu mi, o níláti bá mi kìlọ̀ fún wọn. +Bí mo bá wí fún eniyan burúkú pé yóo kú, tí o kò sì kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀, eniyan burúkú náà yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ọwọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. +Ṣugbọn bí ìwọ bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀, tí kò sì yipada, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ ti gba ẹ̀mí ara tìrẹ là. +Ọlọrun Fi Isikiẹli Ṣe Aṣọ́de ní Israẹli. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +‘Mo lòdì sí ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, n óo sì bèèrè àwọn aguntan mi lọ́wọ́ yín. N óo da yín dúró lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́-aguntan, ẹ kò sì ní rí ààyè bọ́ ara yín mọ́. N óo gba àwọn aguntan mi lẹ́nu yín, ẹ kò sì ní rí wọn pa jẹ mọ́.’ ” +OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Èmi fúnra mi ni n óo wá àwọn aguntan mi, àwárí ni n óo sì wá wọn. +Bí olùṣọ́-aguntan tií wá àwọn aguntan rẹ̀ tí ó bá jẹ lọ, bẹ́ẹ̀ ni n óo wá àwọn aguntan mi, n óo sì yọ wọ́n kúrò ninu gbogbo ibi tí wọ́n fọ́nká sí ní ọjọ́ tí ìkùukùu bo ilẹ̀, tí òkùnkùn sì ṣú. +N óo mú wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ tiwọn. N óo máa bọ́ wọn lórí àwọn òkè Israẹli, lẹ́bàá orísun omi ati gbogbo ibi tí àwọn eniyan ń gbé ní Israẹli. +N óo fún wọn ní koríko tí ó dára jẹ, orí òkè Israẹli sì ni wọn óo ti máa jẹ koríko. Níbẹ̀, ninu pápá oko tí ó dára ni wọn óo dùbúlẹ̀ sí; ninu pápá oko tútù, wọn yóo sì máa jẹ lórí àwọn òkè Israẹli. +Èmi fúnra mi ni n óo jẹ́ olùṣọ́ àwọn aguntan mi, n óo sì mú wọn dùbúlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun sọ. +“N óo wá àwọn tí ó sọnù, n óo sì mú àwọn tí wọ́n ṣáko lọ pada, n óo tọ́jú ọgbẹ́ àwọn tí wọ́n farapa, n óo fún àwọn tí kò lókun lágbára, ṣugbọn àwọn tí wọ́n sanra ati àwọn tí wọ́n lágbára ni n óo parun, nítorí òtítọ́ inú ni n óo fi ṣọ́ àwọn aguntan mi. +“Ní tiyín, ẹ̀yin agbo ẹran mi, èmi OLUWA Ọlọrun ni n óo ṣe ìdájọ́ láàrin aguntan kan ati aguntan keji, ati láàrin àgbò ati òbúkọ. +Ṣé kí ẹ máa jẹ oko ninu pápá dáradára kò to yín ni ẹ ṣe ń fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù yín mọ́lẹ̀? Ṣé kí ẹ mu ninu omi tí ó tòrò kò to yín ni ẹ ṣe fẹsẹ̀ da omi yòókù rú? +Ṣé àjẹkù tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀ ni ó yẹ kí àwọn aguntan tèmi máa jẹ; omi àmukù tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ dàrú sì ni ó yẹ kí wọn máa mu? +“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o fi bá àwọn olùṣọ́-aguntan Israẹli wí, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá àwọn olórí Israẹli wí pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Háà, ẹ̀yin olórí Israẹli tí ẹ̀ ń wá oúnjẹ fún ara yín, ṣé kò yẹ kí olùṣọ́-aguntan máa pèsè oúnjẹ fún àwọn aguntan rẹ̀? +“Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun, ń sọ fun yín ni pé: mo ṣetán tí n óo ṣe ìdájọ́ fún àwọn aguntan tí ó sanra ati àwọn aguntan tí kò lókun ninu. +Nítorí pé ẹ̀ ń fi ẹ̀gbẹ́ ti àwọn tí wọn kò lágbára sọnù, ẹ sì ń kàn wọ́n níwo títí tí ẹ fi tú wọn ká. +N óo gba àwọn aguntan mi sílẹ̀, wọn kò ní jẹ́ ìjẹ mọ́, n óo sì ṣe ìdájọ́ láàrin aguntan kan ati aguntan keji. +Olùṣọ́ kanṣoṣo ni n óo yàn fún wọn, òun náà sì ni Dafidi, iranṣẹ mi. Yóo máa bọ́ wọn, yóo sì máa ṣe olùṣọ́ wọn. +Èmi OLUWA ni n óo jẹ́ Ọlọrun wọn; Dafidi, iranṣẹ mi ni yóo sì jẹ́ ọba láàrin wọn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +N óo bá wọn dá majẹmu alaafia; n óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, wọn yóo máa gbé inú aṣálẹ̀ ati inú igbó láìléwu. +“N óo bukun àwọn, ati gbogbo agbègbè òkè mi. N óo máa jẹ́ kí òjò máa rọ̀ lásìkò wọn, òjò ibukun ni yóo sì máa jẹ́. +Igi inú oko yóo máa so; ilẹ̀ yóo sì máa mú ọpọlọpọ irúgbìn jáde. Àwọn eniyan óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà wọn, tí mo bá sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú. +Wọn kò ní jẹ́ ìjẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko ilẹ̀ yìí kò ní pa wọ́n jẹ mọ́. Wọn óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, ẹnìkan kan kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́. +N óo fún wọn ní ọpọlọpọ nǹkan kórè ninu ohun tí wọ́n bá gbìn, ìyàn kò ní run wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ náà, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kò sì ní fi wọ́n ṣẹ̀sín mọ́. +Ẹ̀yin ń jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ̀ ń fi irun aguntan bo ara yín, ẹ̀ ń pa aguntan tí ó sanra jẹ; ṣugbọn ẹ kò fún àwọn aguntan ní oúnjẹ. +Wọn óo mọ̀ pé èmi, OLUWA Ọlọrun wọn, wà pẹlu wọn, ati pé àwọn ọmọ Israẹli sì ni eniyan mi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Ẹ̀yin aguntan mi, aguntan pápá mi, ẹ̀yin ni eniyan mi; èmi sì ni Ọlọrun yín.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀. +Ẹ kò tọ́jú àwọn tí wọn kò lágbára, ẹ kò tọ́jú àwọn tí ń ṣàìsàn, ẹ kò tọ́jú ẹsẹ̀ àwọn tí wọn dá lẹ́sẹ̀, ẹ kò mú àwọn tí wọn ń ṣáko lọ pada wálé; ẹ kò sì wá àwọn tí wọ́n sọnù. Pẹlu ipá ati ọwọ́-líle ni ẹ fi ń ṣe àkóso wọn. +Nítorí náà, wọ́n túká nítorí pé wọn kò ní olùṣọ́, wọ́n sì di ìjẹ fún àwọn ẹranko burúkú. +Àwọn aguntan mi túká, wọ́n ń káàkiri lórí gbogbo òkè ńlá ati gbogbo òkè kéékèèké. Àwọn aguntan mi fọ́n káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé. Kò sí ẹni tí ó bèèrè wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó wá wọn.’ +“Nítorí náà, ẹ̀yin, olùṣọ́-aguntan, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí. +OLUWA Ọlọrun fi ara rẹ̀ búra ó ní, ‘Àwọn aguntan mi di ìjẹ, fún gbogbo ẹranko nítorí pé wọn kò ní olùṣọ́; nítorí pé àwọn tí ń ṣọ́ wọn kò wá wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ oúnjẹ ni wọ́n ń wá sẹ́nu ara wọn, wọn kò bọ́ àwọn aguntan mi.’ +Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan: +Àwọn Olùṣọ́-Aguntan Israẹli. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“ ‘Nítorí ẹ̀yin ará Edomu sọ pé, àwọn orílẹ̀-èdè mejeeji wọnyi ati ilẹ̀ wọn yóo di tiyín ati pé ẹ óo jogún rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA wà níbẹ̀. +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra, bí ẹ ti fi ìrúnú ati owú ṣe sí wọn nítorí pé ẹ kórìíra wọn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni èmi náà óo ṣe sí ọ; n óo sì jẹ́ kí ẹ mọ irú ẹni tí mo jẹ́ nígbà tí mo bá dájọ́ fun yín. +Ẹ óo mọ̀ pé èmi OLUWA gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ̀ ń sọ sí àwọn òkè Israẹli, pé wọ́n ti di ahoro ati ìkógun fun yín. +Ẹ̀ ń fi ẹnu yín sọ̀rọ̀ ìgbéraga sí mi, ẹ sì ń dá àpárá lù mí; gbogbo rẹ̀ ni mo gbọ́.’ ” +OLUWA Ọlọrun ní, “N óo sọ ìwọ Edomu di ahoro, kí gbogbo ayé lè yọ̀ ọ́; +bí o ti yọ ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ilé wọn di ahoro. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ọ, ìwọ náà óo di ahoro. Gbogbo òkè Seiri ati gbogbo ilẹ̀ Edomu yóo di ahoro. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +“Ìwọ ọmọ eniyan, dojú kọ òkè Seiri, kí o sì fi àsọtẹ́lẹ̀ bá a wí. +Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní,‘Wò ó! Mo lòdì sí ọ,ìwọ Òkè Seiri.N óo nawọ́ ibinu sí ọ,n óo sọ ọ́ di ahoro ati aṣálẹ̀. +N óo sọ àwọn ìlú rẹ di aṣálẹ̀ìwọ pàápàá yóo sì di ahoro;o óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. +“ ‘Nítorí pé ò ń fẹ́ràn ati máa ṣe ọ̀tá lọ títí, o sì fa àwọn ọmọ Israẹli fún ogun pa nígbà tí ìṣòro dé bá wọn, tí wọn ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra pé, n óo fi ọ́ fún ikú pa, ikú yóo máa lépa rẹ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́; ikú yóo máa lépa ìwọ náà. +N óo sọ òkè Seiri di aṣálẹ̀ ati ahoro. N óo pa gbogbo àwọn tí ń lọ tí ń bọ̀ níbẹ̀. +N óo da òkú sí orí àwọn òkè ńláńlá rẹ, yóo kún. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn òkè kéékèèké rẹ, ati gbogbo àwọn àfonífojì rẹ, ati gbogbo ipa odò rẹ. Òkú àwọn tí a fi idà pa ni yóo kúnbẹ̀. +N óo sọ ọ́ di ahoro títí lae, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú àwọn ìlú rẹ mọ́. O óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA. +Ìyà Tí Ọlọrun óo Fi Jẹ Edomu. +OLUWA ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá àwọn òkè Israẹli wí. Sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí: +N óo sọ àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé orí yín di pupọ. Àwọn ìlú yóo rí ẹni máa gbé inú wọn, wọn óo sì tún gbogbo ibi tí ó ti wó kọ́. +N óo sọ eniyan ati ẹran ọ̀sìn di pupọ lórí yín, wọn óo máa bímọlémọ, wọn ó sì di ọ̀kẹ́ àìmọye. N óo mú kí eniyan máa gbé orí yín bí ìgbà àtijọ́, nǹkan ó sì dára fun yín ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA. +N óo jẹ́ kí àwọn eniyan mi, àní àwọn ọmọ Israẹli, máa rìn bọ̀ lórí yín. Àwọn ni wọn óo ni yín, ẹ óo sì di ogún wọn, ẹ kò ní pa wọ́n lọ́mọ mọ́. +“Nítorí àwọn eniyan ń wí pé ò ń paniyan, ati pé ò ń run àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ. +Nítorí náà, o kò ní pa eniyan mọ́, o kò sì ní pa àwọn eniyan rẹ lọ́mọ mọ́, Èmi OLUWA Ọlọrun ni ó sọ bẹ́ẹ̀. +N kò ní jẹ́ kí o gbọ́ ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan kò ní dójútì ọ́ mọ́, n kò sì ní mú kí orílẹ̀-èdè rẹ kọsẹ̀ mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ìwọ ọmọ eniyan, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ilẹ̀ wọn, wọ́n fi ìwà burúkú ba ilẹ̀ náà jẹ́. Lójú mi, ìwà wọn dàbí ìríra obinrin tí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́. +Mo bá bínú sí wọn gan-an nítorí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà ati oriṣa tí wọ́n fi bà á jẹ́. +Mo fọ́n wọn ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n sì tú káàkiri orí ilẹ̀ ayé. Ìwà ati ìṣe wọn ni mo fi dá wọn lẹ́jọ́. +Àwọn ọ̀tá ń yọ̀ yín, wọ́n ń sọ pé, àwọn òkè àtijọ́ ti di ogún àwọn.’ +Nígbà tí wọ́n dé orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, wọ́n bà mí lórúkọ jẹ́, nítorí àwọn eniyan ń sọ nípa wọn pé, ‘Eniyan OLUWA ni àwọn wọnyi, sibẹsibẹ wọ́n kúrò lórí ilẹ̀ OLUWA.’ +Ṣugbọn mo ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi, tí àwọn ọmọ Israẹli sọ di nǹkan yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà. +“Nítorí náà, OLUWA ní kí n pe ẹ̀yin, ọmọ Israẹli, kí n sọ fun yín pé, òun OLUWA Ọlọrun ní, Kì í ṣe nítorí tiyín ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe, bíkòṣe nítorí orúkọ mímọ́ mi, tí ẹ̀ ń bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ sálọ. +N óo fihàn bí orúkọ ńlá mi, tí ó ti bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ti jẹ́ mímọ́ tó, àní orúkọ mi tí ẹ bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ wà. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun, nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ yín fi bí orúkọ mi ti jẹ́ mímọ́ tó hàn wọ́n. +Nítorí pé n óo ko yín jáde láti inú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo gba yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì mu yín pada sórí ilẹ̀ yín. +N óo wọ́n omi mímọ́ si yín lórí, àìmọ́ yín yóo sì di mímọ́. N óo wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu gbogbo ìbọ̀rìṣà yín. +N óo fun yín ní ọkàn titun, n óo sì fi ẹ̀mí titun si yín ninu. N óo yọ ọkàn tí ó le bí òkúta kúrò, n óo sì fun yín ní ọkàn tí ó rọ̀ bí ẹran ara. +N óo fi ẹ̀mí mi si yín ninu, n óo mú kí ẹ máa rìn ní ìlànà mi, kí ẹ sì máa fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́. +Ẹ óo sì máa gbé orí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín. Ẹ óo jẹ́ eniyan mi, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun yín. +N óo gbà yín kúrò ninu gbogbo ìwà èérí yín. N óo mú ọkà pọ̀ ní ilé yín, n kò sì ní jẹ́ kí ìyàn mu yín mọ́. +“Nítorí náà, ó ní kí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé òun OLUWA Ọlọrun ní nítorí pé wọ́n ti sọ ẹ̀yin òkè Israẹli di ahoro, wọ́n sì ja yín gbà lọ́tùn-ún lósì, títí tí ẹ fi di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, àwọn eniyan sì ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní ìsọkúsọ, +N óo jẹ́ kí èso igi ati èrè oko pọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ìtìjú kò ní ba yín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mọ́ nítorí ìyàn. +Nígbà náà ni ẹ óo ranti ìrìnkurìn ati ìwà burúkú yín, ara yín óo sì su yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ati ìwà ìríra yín. +Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájú pé kì í ṣe nítorí yín ni n óo fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ojú tì yín, kí ẹ sì dààmú nítorí ìwà yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ tí mo bá wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín, n óo jẹ́ kí àwọn eniyan máa gbé inú àwọn ìlú yín, n óo sì mú kí wọ́n tún àwọn ibi tí ó wó lulẹ̀ kọ́. +A óo dá oko sórí àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti di igbó, dípò kí ó máa wà ní igbó lójú àwọn tí wọn ń kọjá lọ. +Wọn yóo wí pé, ‘Ilẹ̀ yìí, tí ó ti jẹ́ igbó nígbà kan rí, ti dàbí ọgbà Edẹni, àwọn eniyan sì ti ń gbé àwọn ìlú tí wọ́n ti wó lulẹ̀, tí wọ́n ti di ahoro, tí wọ́n sì ti run tẹ́lẹ̀; a sì ti mọ odi wọn pada.’ +Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín yóo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi OLUWA ni mo tún àwọn ibùgbé yín tí ó wó lulẹ̀ kọ́, tí mo sì tún gbin nǹkan ọ̀gbìn sí ilẹ̀ yín tí ó di igbó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Ohun kan tí n óo tún mú kí àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ mi pé kí n ṣe fún àwọn ni pé kí n máa mú kí àwọn ọmọ wọn pọ̀ sí i bí ọ̀wọ́ aguntan. +Kí wọn pọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran, àní bí ọ̀wọ́ ẹran ìrúbọ tíí pọ̀ ní Jerusalẹmu ní àkókò àjọ̀dún. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìlú tí a ti wó palẹ̀ yóo kún fún ọ̀pọ̀ eniyan. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí èmi OLUWA wí, kí ẹ̀yin òkè ńláńlá ati ẹ̀yin òkè kéékèèké Israẹli, ẹ̀yin ipa odò ati ẹ̀yin àfonífojì, ẹ̀yin ibi tí ẹ ti di aṣálẹ̀ ati ẹ̀yin ìlú tí ẹ ti di ahoro, ẹ̀yin ìlú tí ẹ di ìjẹ ati yẹ̀yẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n yi yín ká. +“N óo fi ìtara sọ̀rọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ati gbogbo Edomu, tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ pẹlu ọkàn ìkórìíra sọ ilẹ̀ mi di ogún wọn, kí wọ́n lè gbà á, kí wọ́n sì pín in mọ́wọ́, nítorí wọ́n rò pé ilẹ̀ mi ti di tiwọn. +“Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli. Wí fún àwọn òkè ńláńlá ati àwọn òkè kéékèèké, ati àwọn ipa odò ati àwọn àfonífojì, pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ìtara ati ìgbónára ni mo fi ń sọ̀rọ̀ nítorí pé ẹ ti jìyà pupọ, ẹ sì ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. +Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ń ṣe ìbúra pé, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín yóo di ẹni ẹ̀sín. +Ṣugbọn ẹ̀yin òkè Israẹli, igi óo hù lórí yín, wọn óo sì so èso fún Israẹli, àwọn eniyan mi, nítorí pé wọn kò ní pẹ́ pada wálé. +Nítorí pé mo wà fun yín, n óo ṣí ojú àánú wò yín, wọn óo dá oko sórí yín, wọn óo sì gbin nǹkan sinu rẹ̀. +Ibukun Ọlọrun Lórí Israẹli. +Agbára OLUWA sọ̀kalẹ̀ sára mi, ẹ̀mí rẹ̀ sì gbé mi wá sinu àfonífojì tí ó kún fún egungun. +Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí ó ti pàṣẹ fún mi. Èémí wọ inú wọn, wọ́n sì di alààyè; ogunlọ́gọ̀ eniyan ni wọ́n, wọ́n bá dìde dúró! +OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọmọ Israẹli ni àwọn egungun wọnyi. Wọ́n ń sọ pé, ‘Egungun wa ti gbẹ; kò sí ìrètí fún wa mọ́, a ti pa wá run patapata.’ +Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘N óo ṣí ibojì yín; n óo sì gbe yín dìde, ẹ̀yin eniyan mi, n óo mu yín pada sí ilé, ní ilẹ̀ Israẹli. +Ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo bá ṣí ibojì yín, tí mo sì gbe yín dìde, ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA. +N óo fi ẹ̀mí mi sinu yín, ẹ óo sì tún wà láàyè; n óo sì mu yín wá sí ilẹ̀ yín. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀, tí mo sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ ” +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ìwọ ọmọ eniyan, mú igi kan kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Igi Juda ati àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’ Mú igi mìíràn kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Ti Josẹfu, (igi Efuraimu) ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’ +Fi ẹnu wọn ko ara wọn, kí wọ́n di igi kan lọ́wọ́ rẹ. +Bí àwọn eniyan rẹ bá bi ọ́ pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí ò ń ṣe yìí? +Wí fún wọn pé èmi OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo mú igi Josẹfu ati àwọn ìdílé Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, n óo fi ẹnu rẹ̀ ko ẹnu igi Juda; n óo sọ wọ́n di igi kan, wọn yóo sì di ọ̀kan lọ́wọ́ mi.’ +Ó mú mi la ààrin wọn kọjá; àwọn egungun náà pọ̀ gan-an ninu àfonífojì náà; wọ́n sì ti gbẹ. +“Mú àwọn igi tí o kọ nǹkan sí lára lọ́wọ́, lójú wọn, +kí o sọ fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ wò ó! N óo kó àwọn ọmọ Israẹli jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà, n óo kó wọn jọ láti ibi gbogbo wá sí ilẹ̀ wọn. +N óo sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan ní orí òkè Israẹli, ọba kanṣoṣo ni yóo sì jẹ lé gbogbo wọn lórí. Wọn kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè meji mọ́; wọn kò ní pín ara wọn sí ìjọba meji mọ́. +Wọn kò ní fi ìbọ̀rìṣà kankan, tabi ìwà ìríra kankan tabi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, sọ ara wọn di aláìmọ́ mọ́. N óo gbà wọ́n ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìfàsẹ́yìn tí wọ́n ti dá. N óo wẹ̀ wọ́n mọ́, wọn yóo máa jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn. +Dafidi, iranṣẹ mi ni yóo jọba lórí wọn; gbogbo wọn óo ní olùṣọ́ kan. Wọn óo máa pa òfin mi mọ́, wọn óo sì máa fi tọkàntọkàn rìn ní ìlànà mi. +Wọn óo máa gbé ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu iranṣẹ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín gbé. Àwọn ati àwọn ọmọ wọn ati àwọn ọmọ ọmọ wọn yóo máa gbé ibẹ̀ títí lae. Dafidi iranṣẹ mi ni yóo sì jẹ́ ọba wọn títí lae. +N óo bá wọn dá majẹmu alaafia, tí yóo jẹ́ majẹmu ayérayé. N óo bukun wọn, n óo jẹ́ kí wọn pọ̀ sí i, n óo sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ sí ààrin wọn títí lae. +N óo kọ́ ibùgbé mi sí ààrin wọn, n óo jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi. +Àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo ya Israẹli sọ́tọ̀, nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà láàrin wọn títí lae.’ ” +OLUWA bá bi mí léèrè, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn egungun wọnyi lè tún jí?”Mo bá dáhùn, mo ní, “OLUWA, ìwọ nìkan ni o mọ̀.” +Ó bá sọ fún mi pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn egungun wọnyi, kí o wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ wọnyi, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí’. +Ó ní: ‘N óo mú kí èémí wọ inú yín, ẹ óo sì di alààyè. +N óo fi iṣan bò yín lára; lẹ́yìn náà n óo fi ara ẹran bò yín, n óo sì da awọ bò yín lára. N óo wá fi èémí si yín ninu, ẹ óo di alààyè, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ” +Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Bí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tán, mo bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ariwo ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀, àwọn egungun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí so mọ́ ara wọn; egungun ń so mọ́ egungun. +Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, iṣan ti dé ara wọn, ẹran ti bo iṣan, awọ ara sì ti bò wọ́n, ṣugbọn kò tíì sí èémí ninu wọn. +OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún èémí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Wá, ìwọ èémí láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé, kí o fẹ́ sinu àwọn òkú wọnyi, kí wọ́n di alààyè.’ ” +Àfonífojì Tí ó kún fún Egungun Gbígbẹ. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, +OLUWA Ọlọrun ní, ��Ní ọjọ́ náà èròkerò yóo wá sí ọkàn rẹ, +o óo wí ninu ara rẹ pé, ‘N óo gbógun ti ilẹ̀ tí kò ní odi yìí; n óo kọlu àwọn tí wọ́n jókòó jẹ́ẹ́jẹ́ wọn láìléwu, gbogbo wọn ń gbé ìlú tí kò ní odi, kò sì ní ìlẹ̀kùn, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn.’ +N óo lọ kó wọn lẹ́rù, n óo sì kó ìkógun. N óo kọlu àwọn ilẹ̀ tí ó ti di ahoro nígbà kan rí, ṣugbọn tí àwọn eniyan ń gbé ibẹ̀ nisinsinyii, àwọn eniyan tí a ṣà jọ láti ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, ṣugbọn tí wọ́n ní mààlúù ati ohun ìní, tí wọ́n sì ń gbé ìkóríta ilẹ̀ ayé. +Ṣeba ati Dedani ati àwọn oníṣòwò Taṣiṣi, ati àwọn ìlú agbègbè wọn yóo bi ọ́ pé, ‘Ṣé o wá kó ìkógun ni, ṣé o kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ láti wá kó ẹrú, fadaka ati wúrà, ati mààlúù, ọrọ̀ ati ọpọlọpọ ìkógun?’ ” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní kí n fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí pé, OLUWA Ọlọrun ní: “Ní ọjọ́ tí àwọn eniyan mi, àwọn ọmọ Israẹli, bá ń gbé láìléwu, ìwọ óo gbéra ní ààyè rẹ +ní ọ̀nà jíjìn, ní ìhà àríwá, ìwọ ati ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn lórí ẹṣin, ọpọlọpọ eniyan, àní, àwọn ọmọ ogun. +O óo kọlu àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan mi, bí ìkùukùu tí ń ṣú bo ilẹ̀. Nígbà tí ó bá yà n óo mú kí o kọlu ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lè mọ̀ mí nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ ìwọ Gogu fi bí ìwà mímọ́ mi ti rí hàn níṣojú wọn. +OLUWA ní: ṣé ìwọ ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà àtijọ́ láti ẹnu àwọn wolii Israẹli, àwọn iranṣẹ mi, tí wọ́n ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọpọlọpọ ọdún pé n óo mú ọ wá láti gbógun tì wọ́n? +“Ṣugbọn ní ọjọ́ tí Gogu bá gbógun ti ilẹ̀ Israẹli, inú mi óo ru. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Pẹlu ìtara ati ìrúnú ni mo fi ń sọ pé ilẹ̀ Israẹli yóo mì tìtì ní ọjọ́ náà. +ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí Gogu, ní ilẹ̀ Magogu; tí ó jẹ́ olórí Meṣeki ati Tubali, +Àwọn ẹja inú omi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko inú igbó, gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ati gbogbo eniyan tí ó wà láyé yóo wárìrì. Àwọn òkè yóo wó lulẹ̀, àwọn òkè etí òkun yóo ṣubú sinu òkun. Gbogbo odi ìlú yóo sì wó lulẹ̀. +N óo dá oríṣìíríṣìí ẹ̀rù ba Gogu, lórí òkè mi, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo fa idà yọ sí ara wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +N óo sì fi àjàkálẹ̀ àrùn ati ikú ogun ṣe ìdájọ́ wọn. N óo rọ òjò yìnyín, iná, ati imí ọjọ́ lé òun, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati ọpọlọpọ eniyan pupọ tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lórí. +N óo fi títóbi mi ati ìwà mímọ́ mi hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè, wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +kí o sì fi àsọtẹ́lẹ̀ bá a wí, pé OLUWA Ọlọrun ní, Mo lòdì sí ọ, ìwọ Gogu, olórí Meṣeki ati Tubali. +N óo yí ojú rẹ pada, n óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu, n óo sì mú ọ jáde, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ, ati àwọn ati ẹṣin wọn, gbogbo wọn, tàwọn ti ihamọra wọn, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ní asà ati apata, tí wọ́n sì ń fi idà wọn. +Àwọn ará Pasia, ati àwọn ará Kuṣi, ati àwọn ará Puti wà pẹlu rẹ̀; gbogbo wọn, tàwọn ti apata ati àṣíborí wọn. +Gomeri ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati Beti Togama láti òpin ilẹ̀ ìhà àríwá ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀; bẹ́ẹ̀ náà ni ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, wọ́n wà pẹlu rẹ̀. +Dira ogun, kí o sì wà ní ìmúrasílẹ̀, ìwọ ati gbogbo eniyan tí wọ́n pé yí ọ ká, kí o jẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ fún wọn. +Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́ a óo ko yín jọ. Ní ọdún mélòó kan sí i, ẹ óo gbógun ti ilẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ̀ sípò lẹ́yìn ìparun ogun, orílẹ̀-èdè tí a ṣà jọ láti ààrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè mìíràn sórí àwọn òkè ńláńlá Israẹli, ilẹ̀ tí ó ti wà ní ahoro fún ọpọlọpọ ọdún. Láti inú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ni a ti ṣa àwọn eniyan rẹ̀ jọ; nisinsinyii, gbogbo wọn wà láìléwu. +Ẹ óo gbéra, ẹ óo máa bọ̀ bí ìjì líle, ẹ óo dàbí ìkùukùu tí ó bo ilẹ̀, ìwọ ati gbogbo ọmọ ogun rẹ, pẹlu ọpọlọpọ eniyan tí ó wà pẹlu rẹ.” +Gogu Gẹ́gẹ́ Bí Ohun Èlò Ọlọrun. +OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Mo lòdì sí ọ́, ìwọ Gogu, ìwọ tí o jẹ́ olórí Meṣeki ati Tubali. +Fún ọdún meje yìí, ẹnìkan kò ní ṣẹ́ igi ìdáná lóko, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gé igi ninu igbó kí wọ́n tó dáná; ohun ìjà ogun ni wọn yóo máa fi dáná. Wọn yóo kó ẹrù àwọn tí wọ́n ti kó wọn lẹ́rù rí; wọn yóo fi ogun kó àwọn ìlú tí wọ́n ti fi ogun kó wọn rí. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA ní, “Tí ó bá di ìgbà náà, n óo fún Gogu ní ibi tí wọn yóo sin ín sí ní Israẹli, àní àfonífojì àwọn arìnrìnàjò tí ó wà ní ìlà oòrùn Òkun Iyọ̀. Yóo dínà mọ́ àwọn arìnrìnàjò nítorí níbẹ̀ ni a óo sin Gogu ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ sí. A óo sì máa pè é ní àfonífojì Hamoni Gogu. +Oṣù meje ni yóo gba àwọn ọmọ Israẹli láti sin òkú wọn, kí wọ́n baà lè fọ ilẹ̀ náà mọ́. +Gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà ni yóo sin wọ́n, wọn óo sì gbayì ní ọjọ́ náà, nígbà tí mo bá fi ògo mi hàn. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +Lẹ́yìn oṣù meje wọn yóo yan àwọn kan tí wọn óo la ilẹ̀ náà já, tí wọn óo máa wá òkú tí ó bá kù nílẹ̀, tí wọn óo sì máa sin wọ́n kí wọ́n lè sọ ilẹ̀ náà di mímọ́. +Bí ẹnìkan ninu àwọn tí ń wá òkú kiri bá rí egungun eniyan níbìkan, yóo fi àmì sibẹ títí tí àwọn tí ń sin òkú yóo fi wá sin ín ní àfonífojì Hamoni Gogu. +Ìlú kan yóo wà níbẹ̀ tí yóo máa jẹ́ Hamoni. Bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe fọ ilẹ̀ náà mọ́.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ké pe oniruuru ẹyẹ ati gbogbo ẹranko igbó, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbá ara yín jọ, kí ẹ máa bọ̀ láti gbogbo àyíká tí ẹ wà. Ẹ wá sí ibi ẹbọ ńlá tí mo fẹ́ ṣe fun yín lórí àwọn òkè Israẹli. Ẹ óo jẹ ẹran, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀. +Ẹ óo jẹ ẹran ara àwọn akikanju, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọba ilẹ̀ ayé, bíi ti àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan, ati ewúrẹ́ ati àwọn mààlúù rọ̀bọ̀tọ̀ Baṣani. +Ẹ óo jẹ ọ̀rá ní àjẹyó, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ ní àmuyó ní ibi àsè tí n óo sè fun yín. +N óo yí ọ pada, n óo lé ọ siwaju, n óo mú ọ wá láti òpin ìhà àríwá, o óo wá dojú kọ àwọn òkè Israẹli. +Ẹ óo jẹ ẹṣin ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n, àwọn alágbára ati oríṣìíríṣìí àwọn ọmọ ogun níbi àsè tí n óo sè fun yín.’ Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“N óo fi ògo mi hàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn ni yóo sì rí irú ẹjọ́ tí mo dá wọn ati irú ìyà tí mo fi jẹ wọ́n. +Láti ìgbà náà lọ, àwọn ọmọ Israẹli óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn. +Àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli dá tí wọ́n fi di ẹni tí ó lọ sí ìgbèkùn, ati pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi ni mo ṣe dijú sí wọn, tí mo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, tí wọ́n sì fi idà pa wọ́n. +Bí àìmọ́ ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni mo fìyà jẹ wọ́n tó, mo sì gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn.” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ṣàánú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli n óo kó àwọn ọmọ Jakọbu pada láti oko ẹrú, n óo ṣàánú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, n óo sì jowú nítorí orúkọ mímọ́ mi. +Wọn yóo gbàgbé ìtìjú wọn ati ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọn hù sí mi, nígbà tí wọn bá ń gbé orí ilẹ̀ wọn láìléwu, tí kò sì sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n. +Nígbà tí mo bá kó wọn pada láti inú oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè, tí mo kó wọn jọ láti ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, n óo fi ara mi hàn bí ẹni mímọ́ lójú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè. +Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, nítorí pé mo kó wọn lọ sí ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, mo sì tún kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn. N kò ní fi ọ̀kankan ninu wọn sílẹ̀ sí ààrin orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́. +N óo tú ẹ̀mí mi lé àwọn ọmọ Israẹli lórí, n ko ní gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Lẹ́yìn náà, n óo gbọn ọrun rẹ dànù lọ́wọ́ òsì rẹ; n óo sì gbọn ọfà bọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ. +Ìwọ, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo kú lórí àwọn òkè Israẹli. N óo fi yín ṣe oúnjẹ fún oniruuru àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko burúkú. +Ninu pápá tí ó tẹ́jú ni ẹ óo kú sí; èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +N óo rọ òjò iná lé Magogu lórí, ati àwọn tí wọn ń gbé láìléwu ní etí òkun, wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA. +N óo sọ orúkọ mímọ́ mi di mímọ̀ láàrin àwọn eniyan mi àwọn ọmọ Israẹli, n kò ní jẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.’ ” +OLUWA Ọl���run ní, “Ẹ wò ó! Ọjọ́ tí mo ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bọ̀, yóo dé. +Àwọn ará ìlú Israẹli yóo tú síta, wọn yóo dáná sun àwọn ohun ìjà ogun: apata ati asà, ọrun ati ọfà, àáké ati ọ̀kọ̀. Ọdún meje ni wọn yóo fi dáná sun wọ́n. +A Ṣẹgun Gogu. +OLUWA ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, mú bulọọku kan kí o gbé e ka iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sórí rẹ̀. +Wíwọ̀n ni o óo máa wọn oúnjẹ tí o óo máa jẹ, ìwọ̀n oúnjẹ òòjọ́ rẹ yóo jẹ́ ogún ṣekeli, ẹ̀ẹ̀kan lojumọ ni o óo sì máa jẹ ẹ́. +Wíwọ̀n ni o óo máa wọn omi tí o óo máa mu pẹlu; ìdá mẹfa òṣùnwọ̀n hini ni omi tí o óo máa mu ní ọjọ́ kan, ẹ̀ẹ̀kan lojumọ ni o óo sì máa mu ún. +O óo jẹ ẹ́ bí àkàrà ọkà baali dídùn; ìgbẹ́ eniyan ni o óo máa fi dá iná tí o óo máa fi dín in lójú wọn.” +OLUWA ní: “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣe máa jẹ oúnjẹ wọn ní àìmọ́, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí òun óo lé wọn sí.” +Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, n kò sọ ara mi di aláìmọ́ rí láti ìgbà èwe mi títí di ìsinsìnyìí, n kò jẹ òkú ẹran rí, tabi ẹran tí ẹranko pa, bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kankan kò kan ẹnu mi rí.” +OLUWA bá wí fún mi pé, “Kò burú, n óo jẹ́ kí o fi ìgbẹ́ mààlúù dáná láti fi dín àkàrà rẹ, dípò ìgbẹ́ eniyan.” +Ó tún fi kun fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, n óo mú kí oúnjẹ wọ́n ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ìbẹ̀rù ni wọn óo máa fi wá oúnjẹ tí wọn óo máa jẹ, wíwọ̀n ni wọn óo sì máa wọn omi mu pẹlu ìpayà. +N óo ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n lè ṣe aláìní oúnjẹ ati omi, kí wọ́n lè máa wo ara wọn pẹlu ìpayà, kí wọ́n sì parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” +Kó àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń dóti ìlú tì í. Bu yẹ̀ẹ̀pẹ̀ sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́ kí ọ̀nà dé ibẹ̀. Fi àgọ́ àwọn jagunjagun sí i, kí o wá gbẹ́ kòtò ńlá yí i ká. +Wá irin pẹlẹbẹ kan tí ó fẹ̀, kí o gbé e sí ààrin ìwọ ati ìlú náà, kí ó dàbí ògiri onírin. Dojú kọ ọ́ bí ìlú tí a gbógun tì; kí o ṣebí ẹni pé ò ń gbógun tì í. Èyí yóo jẹ́ àmì fún ilé Israẹli. +“Lẹ́yìn náà, fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì di ìjìyà àwọn ọmọ ilé Israẹli lé ara rẹ lórí. O óo ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀. +Mo ti fún ọ ní irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390) láti fi ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli. Èyí ni iye ọdún tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀. +Nígbà tí o bá parí iye ọjọ́ yìí, o óo fi ẹ̀gbẹ́ rẹ ọ̀tún lélẹ̀, o óo sì fi ogoji ọjọ́ ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda; ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí o óo fi dùbúlẹ̀ dúró fún ọdún kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀. +“Lẹ́yìn náà, kọjú sí Jerusalẹmu, ìlú tí a gbógun tì, ká aṣọ kúrò ní apá rẹ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i. +Wò ó! N óo dè ọ́ lókùn mọ́lẹ̀, tí o kò fi ní lè yí ẹ̀gbẹ́ pada títí tí o óo fi parí iye ọjọ́ tí o níláti fi gbé ogun tì í. +“Mú alikama ati ọkà baali, ẹ̀wà ati lẹntili, jéró ati ọkà sipẹliti, kí o kó wọn sinu ìkòkò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe burẹdi fún ara rẹ. Òun ni o óo máa jẹ fún irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390), tí o óo fi fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀. +Isikiẹli Gbé Òfin Jáde lórí Ìwà Ìbàjẹ́ ní Jerusalẹmu. +Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kinni, ọdún kẹẹdọgbọn tí a ti wà ní ìgbèkùn, tíí ṣe ọdún kẹrinla tí ogun fọ́ ìlú Jerusalẹmu, agbára OLUWA sọ̀kalẹ̀ sára mi. +Yàrá mẹta mẹta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ẹnu ọ̀nà náà. Bákan náà ni ìwọ̀n àwọn yàrá mẹtẹẹta rí. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìwọ̀n àtẹ́rígbà wọn, ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. +Lẹ́yìn náà, ó wọn ìbú àbáwọlé ẹnu ọ̀nà, ó jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 5). Ó wọn gígùn ẹnu ọ̀nà náà, ó jẹ́ igbọnwọ mẹtala (mita 6½). +Ògiri kan wà níwájú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà, ó ga ní igbọnwọ kan ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. Ati òòró ati ìbú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ igbọnwọ mẹfa mẹfa (mita 3). +Ó wọn ẹnu ọ̀nà náà láti ẹ̀yìn àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ kan títí dé ẹ̀yìn yàrá ẹ̀gbẹ́ keji, ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½), láti ìlẹ̀kùn kinni sí ekeji. +Ó tún wọn ìloro, ó jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Gbọ̀ngàn kan yí ìloro ẹnu ọ̀nà ká +láti iwájú ẹnu ọ̀nà ní àbáwọlé, títí kan ìloro ẹnu ọ̀nà tí ó wà ninu, jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25). +Ẹnu ọ̀nà náà ní àwọn fèrèsé tóóró tóóró yíká, tí ó ga kan àwọn àtẹ́rígbà àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́. Bákan náà, ìloro náà ní àw���n fèrèsé yíká, àwòrán ọ̀pẹ sì wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀. +Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn ti òde, mo rí àwọn yàrá ati pèpéle yíká àgbàlá náà. Ọgbọ̀n yàrá ni ó wà lára àgbàlá náà. +Pèpéle kan wà níbi ẹnu ọ̀nà, tí gígùn rẹ̀ rí bákan náà pẹlu ẹnu ọ̀nà, èyí ni pèpéle tí ó wà ní ìsàlẹ̀. +Ó wọn ibẹ̀ láti inú ẹnu ọ̀nà kúkúrú títí dé iwájú ìta gbọ̀ngàn inú, ó jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ, (mita 45), ní ìhà ìlà oòrùn ati ìhà àríwá. +Ó mú mi lọ sí ilẹ̀ Israẹli ninu ìran, ó gbé mi sí orí òkè gíga kan. Ó dàbí ẹni pé ìlú kan wà ní ìhà ìsàlẹ̀ òkè náà. +Lẹ́yìn náà, ó ṣiwaju mi lọ sí ìhà àríwá; ó wọn ìbú ati òòró ẹnu ọ̀nà kan tí ó wà níbẹ̀ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, tí ó sì ṣí sí àgbàlá òde. +Àwọn yàrá mẹta mẹta wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. Àtẹ́rígbà ati ìloro rẹ̀ rí bákan náà pẹlu àwọn ti ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½). +Àwọn fèrèsé rẹ̀, ati ìloro rẹ̀ ati àwọn àwòrán ọ̀pẹ ara rẹ̀ rí bíi àwọn ti ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Ó ní àtẹ̀gùn meje, ìloro rẹ̀ sì wà ninu. +Níwájú ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá, ni ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn inú wà bí ó ti wà níwájú ẹnu ọ̀nà ti ìlà oòrùn. Ọkunrin náà wọn ibẹ̀ láti ẹnu ọ̀nà kan sí ikeji, ó jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). +Ó mú mi lọ sí apá ìhà gúsù, mo sì rí ẹnu ọ̀nà kan níbẹ̀. Ó wọn àtẹ́rígbà ati ìloro rẹ̀, wọ́n sì rí bákan náà pẹlu àwọn yòókù. +Fèrèsé yí inú ati ìloro rẹ̀ ká, bíi àwọn fèrèsé ti àwọn ẹnu ọ̀nà yòókù. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½). +Ó ní àtẹ̀gùn meje, ìloro rẹ̀ wà ninu, àwòrán ọ̀pẹ sì wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji. +Ẹnu ọ̀nà kan wà ní ìhà gúsù gbọ̀ngàn inú. Ó wọn ibẹ̀, láti ẹnu ọ̀nà náà sí ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà gúsù, jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). +Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn inú, lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà ìhà gúsù, ó sì wọn ẹnu ọ̀nà náà, bákan náà ni òòró ati ìbú rẹ̀ pẹlu àwọn yòókù. +Bákan náà sì ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ́rígbà rẹ̀ ati ìloro rẹ̀ pẹlu àwọn yòókù. Fèrèsé wà lára rẹ̀ yíká ninu, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìloro rẹ̀. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½). +Nígbà tí ó mú mi dé ìlú náà, mo rí ọkunrin kan tí àwọ̀ rẹ̀ dàbí idẹ. Ó sì dúró lẹ́nu ọ̀nà, ó mú okùn òwú ati ọ̀pá tí wọ́n fi ń wọn nǹkan lọ́wọ́. +Àwọn ìloro wà yí i ká, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gùn ní igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½), wọ́n sì fẹ̀ ní igbọnwọ marun-un (mita 2½). +Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ. +Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ìhà ìlà oòrùn gbọ̀ngàn inú, ó sì wọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀, bákan náà ni ó rí pẹlu àwọn yòókù. +Bákan náà sì ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ati àtẹ́rígbà, ati ìloro rẹ̀ rí pẹlu àwọn yòókù, fèrèsé wà lára òun náà yíká ninu, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìloro rẹ̀. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½). +Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ. +Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ibi ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà àríwá, ó sì wọ̀n ọ́n, bákan náà ni òun náà rí pẹlu àwọn yòókù. +Bákan náà ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ́rígbà rẹ̀ ati ìloro rẹ̀ rí pẹlu àwọn yòókù, ó sì ní fèrèsé yíká. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½). +Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ. +Yàrá kan wà tí ìlẹ̀kùn rẹ̀ wà ninu ìloro ẹnu ọ̀nà, níbẹ̀ ni wọ́n tí ń fọ ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun. +Tabili meji meji wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìloro ẹnu ọ̀nà náà, lórí wọn ni wọ́n tí ń pa àwọn ẹran ẹbọ sísun, ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi. +Ọkunrin yìí bá pè mí, ó ní: “ìwọ ọmọ eniyan, ya ojú rẹ, kí o máa wòran, ya etí rẹ sílẹ̀, kí o máa gbọ́; sì fi ọkàn sí gbogbo ohun tí n óo fihàn ọ́; nítorí kí n baà lè fihàn ọ́ ni a ṣe mú ọ wá síbí. Gbogbo ohun tí o bá rí ni o gbọdọ̀ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.” +Tabili meji wà ní ìta ìloro náà, ní ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá, tabili meji sì tún wà ní ẹ̀gbẹ́ keji ìloro ẹnu ọ̀nà náà. +Tabili mẹrin wà ninu, mẹrin sì wà ní ìta, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ọ̀nà; gbogbo rẹ̀ jẹ́ tabili mẹjọ. Lórí wọn ni wọ́n tí ń pa ẹran ìrúbọ. +Tabili mẹrin kan tún wà tí wọ́n fi òkúta gbẹ́, tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀ (mita 7), ìbú rẹ̀ náà jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀ (mita 7), ó sì ga ní igbọnwọ kan (bíi ìdajì mita). Lórí rẹ̀ ni wọ́n ń kó àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa ẹran ẹbọ sísun ati ti ẹbọ yòókù sí. +Wọ́n kan àwọn ìkọ́ kan tí ó gùn ní ìwọ̀n àtẹ́lẹwọ́ kan mọ́ ara tabili yíká ninu. Wọn a máa gbé ẹran tí wọn yóo bá fi rúbọ lé orí àwọn tabili náà. +Lẹ́yìn náà ó mú mi wọ gbọ̀ngàn ti inú. Mo rí yàrá meji ninu gbọ̀ngàn yìí: ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá, ó dojú kọ ìhà gúsù, ekeji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìhà gúsù, ó dojú kọ ìhà àríwá. +Ó wí fún mi pé àwọn alufaa tí ń mójútó tẹmpili ni wọ́n ni yàrá tí ó kọjú sí ìhà gúsù. +Yàrá tí ó kọjú sí ìhà àríwá jẹ́ ti àwọn alufaa tí wọn ń mójútó pẹpẹ; àwọn ni àwọn ọmọ Sadoku. Àwọn nìkan ninu ìran Lefi ni wọ́n lè súnmọ́ OLUWA láti rúbọ sí i. +Ó wọn gbọ̀ngàn ti inú, òòró rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45), igun rẹ̀ mẹrẹẹrin dọ́gba, pẹpẹ sì wà níwájú tẹmpili. +Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ìloro tẹmpili, ó sì wọn àtẹ́rígbà rẹ̀. Ó jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un (mita 2½), ní ẹ̀gbẹ́ kinni ati ikeji; ìbú ẹnu ọ̀nà náà jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita 7). Àwọn ògiri rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta mẹta (mita 1½), ní ẹ̀gbẹ́ kinni ati ikeji. +Òòró ìloro náà jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila (mita 5½), àtẹ̀gùn rẹ̀ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, òpó sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji àtẹ́rígbà rẹ̀. +Mo rí ògiri kan tí ó yí ibi tí tẹmpili wà ká. Ọ̀pá ìwọnlẹ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọkunrin tí mo kọ́ rí gùn ní igbọnwọ mẹfa. Igbọnwọ kọ̀ọ̀kan ọ̀pá tirẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan, (ìdajì mita kan). Ó sì wọn ògiri náà. Ó fẹ̀ ní ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ kan, ó sì ga ní ọ̀pá kan, (mita 3). +Lẹ́yìn náà ó lọ sí ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ó gun àtẹ̀gùn tí ó wà níbẹ̀, ó sì wọn àbáwọlé ẹnu ọ̀nà náà; ó jìn ní ìwọ̀n ọ̀pá kan, (mita 3). +Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ náà gùn ní ìwọ̀n ọ̀pá kan, wọ́n sì fẹ̀ ní ìwọ̀n ọ̀pá kan. Àlàfo tí ó wà láàrin àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2½). Àbáwọlé ẹnu ọ̀nà ẹ̀bá ìloro tí ó kọjú sí tẹmpili jẹ́ ọ̀pá kan. +Lẹ́yìn náà ó wọn ìloro ẹnu ọ̀nà tí ó wà ninu, ó jẹ́ igbọnwọ mẹjọ (mita 4), +àtẹ́rígbà rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji, mita kan. Ìloro ẹnu ọ̀nà náà wà ninu patapata. +ÌRAN NÍPA TẸMPILI ỌJỌ́ IWÁJÚ. +Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ibi mímọ́, ó wọn àtẹ́rígbà rẹ̀, ìbú rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji jẹ́ igbọnwọ mẹfa (mita 3). +ati àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ gbọ̀ngàn fẹ̀ ní ogún igbọnwọ (mita 10), yíká gbogbo ẹ̀gbẹ́ tẹmpili. +Àwọn ìlẹ̀kùn àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ṣí sí apá pèpéle tí kò sí ohunkohun lórí rẹ̀. Ìlẹ̀kùn kan kọjú sí ìhà àríwá, ekeji kọjú sí ìhà gúsù. Ìbú pèpéle tí kò sí ohunkohun lórí rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2½) yíká. +Ilé tí ó kọjú sí àgbàlá Tẹmpili ní apá ìwọ̀ oòrùn fẹ̀ ní aadọrin igbọnwọ (mita 35), ògiri ilé náà nípọn ní igbọnwọ marun-un (mita 2½) yíká, òòró rẹ̀ sì jẹ́ aadọrun-un igbọnwọ (mita 45). +Lẹ́yìn náà, ó wọn Tẹmpili, ó gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). Àgbàlá ati ilé náà pẹlu ògiri rẹ̀ gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). +Bákan náà ni gígùn iwájú tẹmpili tí ó kọjú sí ìlà oòrùn ati àgbàlá, òun náà jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). +Lẹ́yìn náà, ó wọn òòró ilé ní ìhà tí ó dojú kọ àgbàlá tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn ati àwọn ògiri rẹ̀; ẹ̀gbẹ́ kinni keji gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).Pákó fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ni wọ́n fi bo ara ògiri ibi mímọ́ jùlọ Tẹmpili náà ati yàrá inú ati +ìloro ti ìta yíká. ��wọn mẹtẹẹta ní fèrèsé aláṣìítì. Wọ́n fi pákó fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo ara ògiri Tẹmpili náà yíká láti ilẹ̀ títí kan ibi fèrèsé, títí kọjá ìloro. (Wọ́n fi pákó bo àwọn fèrèsé náà). +Ati ààyè tí ó wà lókè ẹnu ọ̀nà, títí kan yàrá inú pàápàá, ati ẹ̀yìn ìta. Gbogbo ara ògiri yàrá inú yíká ati ibi mímọ́ ni wọ́n gbẹ́ +àwòrán igi ọ̀pẹ ati kerubu sí yíká; wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ kọ̀ọ̀kan sí ààrin kerubu meji meji. +Kerubu kọ̀ọ̀kan ní iwájú meji meji. Iwájú tí ó dàbí ti eniyan kọjú sí igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ kinni, ekeji tí ó dàbí ti ọ̀dọ́ kinniun kọjú sí igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ keji. Wọ́n gbẹ́ wọn bẹ́ẹ̀ sí ara Tẹmpili yíká. +Ìbú ẹnu ọ̀nà àbáwọlé jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 5), ògiri ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà gùn ní igbọnwọ marun-un marun-un (mita 3), lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji. Ó wọn ibi mímọ́ inú náà: òòró rẹ̀ jẹ́ ogoji igbọnwọ (mita 20), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 10). +Wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ ati kerubu sí ara ògiri náà láti ilẹ̀ títí dé òkè ìlẹ̀kùn. +Àwọn òpó ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn ti òde ibi mímọ́ jùlọ ní igun mẹrin, òòró ati ìbú ìlẹ̀kùn wọn sì dọ́gba.Kinní kan tí ó dàbí +pẹpẹ tí a fi igi ṣe wà níwájú ibi mímọ́. Gíga rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta (mita 1½), òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji (bíi mita kan), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ meji. Igi ni wọ́n fi ṣe igun rẹ̀, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ati ara rẹ̀. Ọkunrin náà sọ fún mi pé: “Èyí ni tabili tí ó wà níwájú OLUWA.” +Ibi mímọ́ jùlọ, ati ibi mímọ́ ní ìlẹ̀kùn meji meji. +Àwọn ìlẹ̀kùn náà ní awẹ́ meji meji. Awẹ́ meji meji tí ó ṣe é ṣí láàrin ni ìlẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan ní. +Wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ ati kerubu sí ara ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ jùlọ, bí èyí tí wọ́n gbẹ́ sí ara àwọn ògiri. Ìbòrí kan tí a fi pákó ṣe wà níwájú ìloro ní ìta. +Àwọn fèrèsé aláṣìítì, tí wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ sí lára, wà lára ògiri ìloro náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji. +Lẹ́yìn náà, ó wọ yàrá inú lọ, ó wọn àtẹ́rígbà ẹnu ọ̀nà, ó jẹ́ igbọnwọ meji (bíi mita kan), ìbú ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà jẹ́ igbọnwọ mẹfa (mita 3), ògiri ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà sì gùn ní igbọnwọ meje (mita 3½). +Ó wọn òòró yàrá náà, ó jẹ́ ogún igbọnwọ, (mita 10), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 10), níwájú ibi mímọ́ náà. Ó sì wí fún mi pé ìhín ni ibi mímọ́ jùlọ. +Lẹ́yìn náà, ó wọn ògiri tẹmpili, ó nípọn ní igbọnwọ mẹfa (mita 3), ìbú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ jẹ́ igbọnwọ mẹrin (bíi mita 2) yípo Tẹmpili náà. +Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ alágbèékà mẹta, ọgbọ̀n yàrá ni ó sì wà ninu àgbékà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n mọ òpó sí ara ògiri Tẹmpili yíká, kí wọn baà lè gba àwọn yàrá dúró kí ó má baà jẹ́ pé ògiri Tẹmpili ni óo gbé wọn ró. +Àwọn yàrá náà ń fẹ̀ sí i láti àgbékà dé àgbékà, bí òpó tí wọ́n mọ sí ara ògiri Tẹmpili ṣe ń tóbi sí i. Àtẹ̀gùn kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Tẹmpili náà tí ó lọ sókè. Ó bẹ̀rẹ̀ láti àgbékà kinni, ó gba inú ti ààrin lọ sí èyí tí ó wà lókè patapata. +Mo rí i pé Tẹmpili náà ní pèpéle tí ó ga yíká. Ìpìlẹ̀ àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ jẹ́ ọ̀pá kan tí ó gùn ní igbọnwọ gígùn mẹfa (mita 3). +Ògiri ìta àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ nípọn ní igbọnwọ marun-un (mita 2½), apá kan pèpéle tí kò ní ohunkohun lórí jẹ́ igbọnwọ marun-un. Láàrin pèpéle Tẹmpili +Àwọn Yàrá Tí Wọ́n Kọ́ sí Ẹ̀gbẹ́ Àwọn Ògiri Tẹmpili. +Lẹ́yìn náà ó mú mi jáde, ó mú mi wọ inú gbọ̀ngàn ti inú lápá ìhà àríwá, ó sì mú mi wọ inú àwọn yàrá tí ó wà níwájú àgbàlá Tẹmpili, ati níwájú ilé tí ó wà ní ìhà àríwá. +Bákan náà, àwọn yàrá kan wà ní ìhà gúsù, lára ògiri òòró àgbàlá ti ìta, wọ́n fara kan àgbàlá tẹmpili, +ọ̀nà wà níwájú wọn. Wọ́n rí bí àwọn yàrá ti ìhà àríwá, òòró ati ìbú wọn rí bákan náà. Bákan náà ni ẹnu ọ̀nà wọn rí, ati ìlẹ̀kùn wọn. +Nísàlẹ̀ àwọn yàrá ìhà gúsù, ọ̀nà kan wà ní apá ìlà oòrùn. Bí eniyan bá wọ àlàfo náà, ògiri kan dábùú rẹ̀ níwájú. +Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà wí fún mi pé, “Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ìhà àríwá ati àwọn yàrá ìhà gúsù tí wọ́n kọjú sí àgbàlá ni àwọn yàrá mímọ́. Níbẹ̀ ni àwọn alufaa tí ń rú ẹbọ sí OLUWA yóo ti máa jẹ ẹbọ mímọ́ jùlọ. Níbẹ̀ ni wọn yóo máa kó àwọn ẹbọ mímọ́ jùlọ sí; ati àwọn ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀��ẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, nítorí ibẹ̀ jẹ́ ibi mímọ́. +Nígbà tí àwọn alufaa bá wọ ibi mímọ́, wọn kò gbọdọ̀ jáde sí gbọ̀ngàn ìta láìbọ́ aṣọ tí wọ́n lò sinu yàrá wọnyi, nítorí pé aṣọ mímọ́ ni wọ́n. Wọ́n gbọdọ̀ wọ aṣọ mìíràn kí wọ́n tó súnmọ́ àwọn ohun tí ó jẹ́ ti gbogbo eniyan.” +Nígbà tí ó ti parí wíwọn inú Tẹmpili, ó mú mi gba ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn jáde, ó sì wọn ẹ̀yìn Tẹmpili yíká. +Ó wọn apá ìlà oòrùn pẹlu ọ̀pá rẹ̀, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀. +Lẹ́yìn náà, ó yipada, ó wọn ìhà àríwá, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀. +Lẹ́yìn náà, ó yipada, ó wọn ìhà gúsù, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀. +Lẹ́yìn náà, ó yipada, ó wọn apá ìwọ̀ oòrùn, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀. +Òòró ilé tí ó wà ní ìhà àríwá náà jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 50), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25). +Ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ni ó wọ̀n. Tẹmpili náà ní ògiri yíká, òòró rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), èyí ni ó jẹ́ ààlà láàrin ibi mímọ́ ati ibi tí ó jẹ́ ti gbogbo eniyan. +Ibùjókòó-òkè meji tí ó kọjú sí ara wọn wà ní àgbékà mẹtẹẹta; wọ́n wà lára ògiri láti nǹkan bíi ogún igbọnwọ sí ara gbọ̀ngàn inú, ati ibi tí ó kọjú sí pèpéle tí ó wà lára gbọ̀ngàn òde. +Ọ̀nà kan wà níwájú àwọn yàrá tí ó lọ sinu, ó fẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 5), ó sì gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 50), àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ wà ní ìhà àríwá. +Àwọn yàrá ti àgbékà kẹta kéré, nítorí ibùjókòó-òkè ti àgbékà kẹta fẹ̀ ju àwọn tí wọ́n wà níwájú àwọn yàrá àgbékà kinni ati ti àgbékà ààrin lọ. +Àgbékà mẹta ni àwọn yàrá náà, ọgbọ̀n yàrá ni ó wà lára ògiri ní àjà kọ̀ọ̀kan, wọn kò sì ní òpó bíi ti gbọ̀ngàn ìta, nítorí náà ni wọ́n ṣe sún àwọn yàrá àgbékà òkè kẹta sinu ju ti àwọn yàrá àgbékà kinni ati ti ààrin lọ. +Ògiri kan wà ní ìta tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ àwọn yàrá ní apá ti gbọ̀ngàn ìta, ó wà níwájú àwọn yàrá náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, (mita 25). +Àwọn yàrá ti gbọ̀ngàn ìta gùn ní aadọta igbọnwọ (mita 25), ṣugbọn àwọn tí wọ́n wà níwájú tẹmpili jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 50). +Nísàlẹ̀ àwọn yàrá wọnyi, ọ̀nà kan wà ní apá ìlà oòrùn bí eniyan bá ti ń bọ̀ láti ibi gbọ̀ngàn ìta. +Àwọn Ilé Meji Tí Wọ́n Wà ní Ẹ̀gbẹ́ Tẹmpili náà. +Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn. +“Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe àpèjúwe Tẹmpili yìí, sọ bí ó ti rí ati àwòrán kíkọ́ rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn lè tì wọ́n. +Bí ojú ohun tí wọ́n ṣe bá tì wọ́n, ṣe àlàyé Tẹmpili náà, bí o ti rí i, ẹnu ọ̀nà àbájáde ati àbáwọlé rẹ̀. Sọ bí o ti rí i fún wọn, sì fi àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ hàn wọ́n. Kọ wọ́n sílẹ̀ lójú wọn, kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ mọ́. +Òfin Tẹmpili nìyí, gbogbo agbègbè tí ó yí orí òkè ńlá tí ó wà ká gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ jùlọ.” +Bí ìwọ̀n pẹpẹ náà ti rí nìyí; irú ọ̀pá kan náà tí ó jẹ́ igbọnwọ kan ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ (ìdajì mita kan) kan ni ó fi wọ̀n ọ́n. Pèpéle pẹpẹ náà yóo ga ní igbọnwọ kan, yóo fẹ̀ ní igbọnwọ kan. Etí rẹ̀ yíká fẹ̀ ní ìka kan (idamẹrin mita kan). +Gíga pẹpẹ láti pèpéle tí ó wà nílẹ̀ títí dé ìtẹ́lẹ̀ ìsàlẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji (mita kan). Ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan (ìdajì mita kan). Láti ìtẹ́lẹ̀ kékeré títí dé ìtẹ́lẹ̀ ńlá jẹ́ igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ibú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan (idaji mita kan). +Orí pẹpẹ náà ga ní igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ìwo mẹrin wà lára rẹ̀, wọ́n gùn ní igbọnwọ kọ̀ọ̀kan (ìdajì mita kan). +Orí pẹpẹ náà ní igun mẹrin, òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mejila (mita mẹfa) ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila (mita mẹfa). +Ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ náà ní igun mẹrin, ó ga ní igbọnwọ mẹrinla (mita meje), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita meje). Etí rẹ̀ yíká jẹ́ ìdajì igbọnwọ (idamẹrin mita), pèpéle rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan yíká (ìdajì mita kan). Àtẹ̀gùn pẹpẹ náà kọjú sí apá ìlà oòrùn. +Ọkunrin náà wí fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Àwọn òfin pẹpẹ nìwọ̀nyí, ní ọjọ́ tí a bá gbé e kalẹ̀ láti máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ ati láti máa ta ẹ̀jẹ̀ sí i lára, +ẹ óo fún àwọn alufaa, ọmọ Lefi, láti inú ìran Sadoku, tí wọn ń rú ẹbọ sí mi, ní akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. +Wò ó! Ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli yọ láti apá ìlà oòrùn, ìró bíbọ̀ rẹ̀ dàbí ti omi òkun, ìmọ́lẹ̀ ògo rẹ̀ sì tàn sórí ilẹ̀. +Ẹ óo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ óo fi sí ara ìwo pẹpẹ ati igun mẹrẹẹrin pèpéle rẹ̀, ati ara etí rẹ̀ yíká, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe wẹ pẹpẹ náà mọ́; bẹ́ẹ̀ ni ètò ìwẹ̀nùmọ́ pẹpẹ lọ. +Ẹ óo mú akọ mààlúù ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; ẹ óo sun ún ní ibi tí a yàn lára ilẹ̀ Tẹmpili ní ìta ibi mímọ́. +Ní ọjọ́ keji ẹ óo fi òbúkọ tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹ ya pẹpẹ náà sí mímọ́ bí ẹ ti fi ẹbọ akọ mààlúù yà á sí mímọ́. +Bí ẹ bá ti yà á sí mímọ́ tán, ẹ óo mú akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ati àgbò tí kò ní àbààwọ́n láti inú agbo ẹran, ẹ óo fi rú ẹbọ. +Ẹ óo kó wọn wá siwaju OLUWA, alufaa yóo wọ́n iyọ̀ lé wọn lórí, yóo sì fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA. +Lojoojumọ, fún ọjọ́ meje, ẹ óo máa mú ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan ati akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n láti inú agbo ẹran, ẹ óo máa fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. +Fún ọjọ́ meje ni ẹ óo fi máa rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ fún pẹpẹ náà tí ẹ óo sì máa yà á sí mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yà á sọ́tọ̀ fún lílò. +Tí ètò àwọn ọjọ́ wọnyi bá ti parí, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹjọ, àwọn alufaa yóo máa rú ẹbọ sísun yín ati ẹbọ alaafia yín lórí pẹpẹ náà, n óo sì máa tẹ́wọ́gbà wọ́n. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” +Ìran tí mo rí yìí dàbí èyí tí mo rí nígbà tí Ọlọrun wá pa ìlú Jerusalẹmu run ati bí ìran tí mo rí létí odò Kebari; mo bá dojúbolẹ̀. +Ìtànṣán ògo OLUWA wọ inú Tẹmpili láti ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. +Ẹ̀mí bá gbé mi dìde, ó mú mi wá sinu gbọ̀ngàn inú; ìtànṣán ògo OLUWA sì kún inú Tẹmpili náà. +Bí ọkunrin náà ti dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, mo gbọ́ tí ẹnìkan ń bá mi sọ̀rọ̀ láti inú Tẹmpili, ó ní: +“Ìwọ ọmọ eniyan, ààyè ìtẹ́ mi nìyí, ati ibi ìgbẹ́sẹ̀lé mi. Níbẹ̀ ni n óo máa gbé láàrin àwọn eniyan Israẹli títí lae. Ilé Israẹli tabi àwọn ọba wọn kò ní fi àgbèrè ẹ̀sìn wọn, ati òkú àwọn ọba wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́. +Wọn kò ní tẹ́ pẹpẹ wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi mọ́, tabi kí wọn gbé òpó ìlẹ̀kùn wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi; tí ó fi jẹ́ pé ògiri kan ni yóo wà láàrin èmi pẹlu wọn. Wọ́n ti fi ìwà ìríra wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́, nítorí náà ni mo ṣe fi ibinu pa wọ́n run. +Kí wọ́n pa ìwà ìbọ̀rìṣà wọn tì, kí wọ́n sì gbé òkú àwọn ọba wọn jìnnà sí mi, n óo sì máa gbé ààrin wọn títí lae. +Ọlọrun Pada Sinu Tẹmpili. +Lẹ́yìn náà ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà ìta ibi mímọ́ tí ó kọjú sí ìlà oòrùn, ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà náà wà ní títì. +OLUWA ní, “Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada lẹ́yìn mi, tí wọ́n ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn nígbà tí Israẹli ṣáko lọ, yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. +Wọ́n lè jẹ́ iranṣẹ ninu ibi mímọ́ mi, wọ́n lè máa ṣe alákòóso àwọn ẹnu ọ̀nà tẹmpili, wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili, wọ́n lè máa pa ẹran ẹbọ sísun ati ẹran ẹbọ àwọn eniyan, wọ́n lè máa ṣe iranṣẹ fún àwọn eniyan. +Nítorí pé wọ́n ti jẹ́ iranṣẹ fún wọn níwájú àwọn oriṣa, wọ́n sì di ohun ìkọsẹ̀ tí ó mú ilé Israẹli dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà, mo ti búra nítorí wọn pé wọ́n gbọdọ̀ jìyà. +Wọn kò gbọdọ̀ dé ibi pẹpẹ mi láti ṣe iṣẹ́ alufaa, wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ mi ati àwọn ohun mímọ́ jùlọ; ojú yóo tì wọ́n nítorí ohun ìríra tí wọ́n ṣe. +Sibẹsibẹ, n óo yàn wọ́n láti máa tọ́jú tẹmpili ati láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ ní ṣíṣe ninu rẹ̀. +“Ṣugbọn àwọn alufaa ọmọ Lefi láti ìran Sadoku, tí wọn ń tọ́jú ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, àwọn ni yóo máa lọ sí ibi pẹpẹ mi láti rúbọ sí mi. Àwọn ni wọn óo máa fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Àwọn ni wọn óo máa wọ ibi mímọ́ mi, wọn óo máa lọ sí ibi tabili mi, tí wọn óo máa ṣiṣẹ́ iranṣẹ, wọn óo sì máa pa àṣẹ mi mọ́. +Bí wọ́n bá ti dé àwọn ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn inú, wọn yóo wọ aṣọ funfun. Wọn kò ní wọ ohunkohun tí a fi irun aguntan hun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ lẹ́nu ọ̀nà ati ninu gbọ̀ngàn inú. +Wọn yóo wé lawani tí a fi aṣọ funfun rán, wọn yóo sì wọ ṣòkòtò aṣọ funfun. Wọn kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń mú kí ooru mú eniyan di ara wọn ní àmùrè. +Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan ní gbọ̀ngàn ìta, wọn yóo bọ́ aṣọ tí wọ́n wọ̀ nígbà tí wọn ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sí àwọn yàrá mímọ́. Wọn yóo wọ aṣọ mìíràn kí wọn má baà sọ àwọn eniyan náà di mímọ́ nítorí ẹ̀wù wọn. +OLUWA wí fún mi pé, “Ìlẹ̀kùn yìí yóo máa wà ní títì ni, wọn kò gbọdọ̀ ṣí i; ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé, nítorí èmi OLUWA, Ọlọrun Israẹli, ti gba ibẹ̀ wọlé. Nítorí náà, títì ni yóo máa wà. +“Wọn kò gbọdọ̀ fá irun orí wọn tabi kí wọn jẹ́ kí oko irun wọn gùn, wọn yóo máa gé díẹ̀díẹ̀ lára irun orí wọn ni. +Kò sí alufaa kan tí ó gbọdọ̀ mu ọtí waini nígbà tí ó bá wọ gbọ̀ngàn inú. +Wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tabi obinrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, àfi wundia tí kò tíì mọ ọkunrin láàrin àwọn eniyan Israẹli tabi opó tí ó jẹ́ aya alufaa. +“Wọ́n gbọdọ̀ kọ́ àwọn eniyan mi láti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn nǹkan mímọ́ tí a yà sọ́tọ̀ ati àwọn nǹkan lásán. Wọ́n sì gbọdọ̀ kọ́ wọn láti mọ ìyàtọ̀ láàrin nǹkan tí kò mọ́ ati àwọn nǹkan mímọ́. +Bí àríyànjiyàn bá bẹ́ sílẹ̀, àwọn ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onídàájọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí èmi gan-an yóo ti ṣe é. Wọ́n gbọdọ̀ pa àwọn òfin ati ìlànà mi mọ́ lákòókò gbogbo àṣàyàn àjọ̀dún wọn, wọ́n sì gbọdọ̀ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́. +“Wọn kò gbọdọ̀ sọ ara wọn di aláìmọ́ nípa sísúnmọ́ òkú, ṣugbọn wọ́n lè sọ ara wọn di aláìmọ́ bí ó bá jẹ́ pé òkú náà jẹ́ ti baba wọn tabi ìyá wọn tabi ti ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin tabi ti arakunrin wọn tí kò tíì gbeyawo tabi arabinrin wọn tí kò tíì wọ ilé ọkọ. +Lẹ́yìn tí alufaa bá di aláìmọ́, yóo dúró fún ọjọ́ meje, lẹ́yìn náà yóo di mímọ́. +Ní ọjọ́ tí ó bá lọ sí ibi mímọ́, tí ó bá lọ sinu gbọ̀ngàn inú láti ṣiṣẹ́ iranṣẹ ní ibi mímọ́, ó gbọdọ̀ rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Wọn kò ní ní ilẹ̀ ìní nítorí èmi ni ìní wọn, ẹ kò ní pín ilẹ̀ fún wọn ní Israẹli, èmi ni ìpín wọn. +Àwọn ni wọn óo máa jẹ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, àwọn ni wọ́n ni gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ ní Israẹli. +Ọba nìkan ni ó lè jókòó níbẹ̀ láti jẹun níwájú OLUWA. Yóo gba ẹnu ọ̀nà ìloro wọlé, ibẹ̀ náà ni yóo sì gbà jáde.” +Gbogbo àkọ́so oniruuru èso ati oniruuru ọrẹ gbọdọ̀ jẹ́ ti àwọn alufaa. Ẹ sì gbọdọ̀ fún àwọn alufaa mi ní àkọ́pò ìyẹ̀fun yín kí ibukun lè wà ninu ilé yín. +Àwọn alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrarẹ̀ tabi tí ẹranko burúkú bá pa, kì báà jẹ́ ẹyẹ tabi ẹranko. +Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà mú mi gba ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá wá siwaju tẹmpili; mo sì rí i tí ìtànṣán ògo OLUWA kún inú tẹmpili, mo bá dojúbolẹ̀. +OLUWA bá sọ fún mi pé: “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe akiyesi dáradára, ya ojú rẹ, kí o sì fi etí sílẹ̀ kí o gbọ́ gbogbo ohun tí n óo sọ fún ọ nípa àṣẹ ati àwọn òfin tí ó jẹ mọ́ tẹmpili OLUWA. Ṣe akiyesi àwọn eniyan tí a lè gbà láàyè kí wọ́n wọ inú tẹmpili ati àwọn tí kò gbọdọ̀ wọlé. +“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olóríkunkun, pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ dáwọ́ àwọn nǹkan ìríra tí ẹ̀ ń ṣe dúró. +Nígbà tí ẹ̀ ń gbà fún àwọn àlejò, tí a kò kọ nílà abẹ́, ati ti ọkàn, láti máa wọ ibi mímọ́ mi nígbà tí ẹ bá ń fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi, ibi mímọ́ mi ni ẹ̀ ń sọ di aláìmọ́. Ẹ ti fi àwọn ohun ìríra yín ba majẹmu mi jẹ́. +Ẹ kò tọ́jú àwọn ohun mímọ́ mi, àwọn àlejò ni ẹ ti fi ṣe alákòóso níbẹ̀. +“ ‘Nítorí náà, ẹni tí kò bá kọlà ọkàn ati ti ara ninu àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” +Lílo Ẹnu Ọ̀nà Ìlà Oòrùn. +“Nígbà tí ẹ bá pín ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan, ẹ ya ilẹ̀ kan sọ́tọ̀ fún OLUWA, tí yóo jẹ́ ilẹ̀ mímọ́. Gígùn rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ. Ilẹ̀ mímọ́ ni gbogbo ilẹ̀ náà yóo jẹ́. +“Òṣùnwọ̀n eefa ati ti bati tí ó péye ni kí ẹ máa lò. +“Òṣùnwọ̀n eefa ati òṣùnwọ̀n bati náà gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà, eefa ati bati yín gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n homeri kan. Òṣùnwọ̀n homeri ni ó gbọdọ̀ jẹ́ òṣùnwọ̀n tí ẹ óo máa fi ṣiṣẹ́. +“Ogún òṣùnwọ̀n gera ni yóo wà ninu òṣùnwọ̀n ṣekeli kan. Ṣekeli marun-un gbọdọ̀ pé ṣekeli marun-un. Ṣekeli mẹ́wàá sì gbọdọ̀ pé ṣekeli mẹ́wàá; òṣùnwọ̀n mina sì gbọdọ̀ pé aadọta ṣekeli. +“Ohun tí ẹ óo máa fi rúbọ sí OLUWA nìwọ̀nyí: ìdámẹ́fà òṣùnwọ̀n eefa kan ninu òṣùnwọ̀n homeri ọkà yín kọ̀ọ̀kan, ati ìdámẹ́fà òṣùnwọ̀n eefa kan ninu òṣùnwọ̀n homeri alikama yín kọ̀ọ̀kan. +Ìwọ̀n òróró gbọdọ̀ péye gẹ́gẹ́ bí ìlànà; ìdámẹ́wàá ìwọ̀n bati mẹ́wàá ni òṣùnwọ̀n bati kan ninu òṣùnwọ̀n kori kọ̀ọ̀kan òṣùnwọ̀n kori gẹ́gẹ́ bíi ti homeri. +Ẹ níláti ya aguntan kọ̀ọ̀kan sọ́tọ̀ ninu agbo ẹran kọ̀ọ̀kan tí ó tó igba ẹran, ninu àwọn agbo ẹran ìdílé Israẹli. Ẹ yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, kí wọ́n lè ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Àwọn ọmọ Israẹli gbọdọ̀ kó àwọn nǹkan ìrúbọ náà fún àwọn ọba Israẹli. +Ọba ni ó gbọdọ̀ máa pèsè ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ ohun mímu ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún, ati àwọn ọjọ́ oṣù tuntun, àwọn ọjọ́ ìsinmi ati àwọn ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Òun ni yóo máa pèsè ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni, ẹ pa ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan tí kò ní àbààwọ́n, kí ẹ fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ ibi mímọ́. +Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo fi sí ara òpó ìlẹ̀kùn tẹmpili, ati orígun mẹrẹẹrin pẹpẹ ati òpó ìlẹ̀kùn àbáwọlé gbọ̀ngàn ààrin ilé. +Ẹ óo fi ààyè sílẹ̀ ninu ilẹ̀ yìí fún Tẹmpili mímọ́, ìbú ati òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ, ẹ óo sì tún fi aadọta igbọnwọ ilẹ̀ sílẹ̀ yí i ká. +Bákan náà ni ẹ gbọdọ̀ ṣe ní ọjọ́ keje oṣù láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀; kí ẹ lè ṣe ètùtù fún tẹmpili. +“Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni, ẹ gbọdọ̀ ṣe ọdún Àjọ Ìrékọjá, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ óo máa jẹ fún ọjọ́ meje. +Ní ọjọ́ náà ọba yóo pa ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ ati fún gbogbo àwọn ará ìlú. +Fún ọjọ́ meje tí ẹ óo fi ṣe àjọ̀dún yìí, yóo mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù meje ati àgbò meje tí kò ní àbààwọ́n wá fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kọ̀ọ̀kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. +Fún ẹbọ ohun jíjẹ yóo pèsè òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan ati òṣùnwọ̀n hini òróró kọ̀ọ̀kan fún òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan. +“Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje, tíí ṣe ọjọ́ keje àjọ̀dún náà, yóo pèsè irú ẹbọ kan náà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró.” +Lára ilẹ̀ mímọ́ náà, ẹ óo wọn apá kan tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 10), níbẹ̀ ni ilé mímọ́ yóo wà, yóo jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ. +Yóo jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà, yóo wà fún àwọn alufaa, tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, tí wọ́n sì ń dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ iranṣẹ. Ibẹ̀ ni wọn yóo kọ́ ilé wọn sí, ibẹ̀ ni yóo sì jẹ́ ilẹ̀ mímọ́ fún ibi mímọ́ mi. +Ẹ wọn ibòmíràn tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 10). Ibẹ̀ ni yóo wà fún àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili, ibẹ̀ ni wọn óo máa gbé. +“Lára ilẹ̀ mímọ́ náà, ẹ óo ya apá kan sọ́tọ̀ tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) igbọnwọ (kilomita 2½), ilẹ̀ yìí yóo wà fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. +“Ọba ni yóo ni ilẹ̀ tí ó yí ilẹ̀ mímọ́ náà ká nì ẹ̀gbẹ́ kinni keji, ati àwọn ilẹ̀ tí ó wà ninu ìlú náà, ní ìwọ̀ oòrùn ati ìlà oòrùn, yóo gùn tó ilẹ̀ ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, yóo bẹ̀rẹ̀ ní òpin ìwọ̀ oòrùn yóo sì dé òpin ìlà oòrùn ilẹ̀ náà. +Yóo jẹ́ ìpín ti ọba ní Israẹli. Àwọn ọba kò gbọdọ̀ ni àwọn eniyan mi lára mọ́, wọ́n gbọdọ̀ fi ilẹ̀ yòókù sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ̀yin ọba Israẹli, ẹ má hùwà ipá ati ìninilára mọ́, ẹ máa hùwà ẹ̀tọ́ ati òdodo, ẹ má lé àwọn eniyan mi jáde mọ́. +Ìpín OLUWA ní Orílẹ̀-Èdè Náà. +OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹnu ọ̀nà àgbàlá inú tí ó kọjú sí ìlà oòrùn gbọdọ̀ wà ní títì fún ọjọ́ mẹfa tí a fi ń ṣiṣẹ́. Ṣugbọn ẹ máa ṣí i ní ọjọ́ ìsinmi ati ọjọ́ oṣù tuntun. +Ọba yóo bá wọn wọlé nígbà tí wọ́n bá wọlé, nígbà tí wọ́n bá sì jáde, yóo bá wọn jáde. +Ní ọjọ́ àsè ati ìgbà àjọ̀dún, ìwọ̀n eefa ọkà kan ni wọn óo fi rúbọ pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù kan, ìwọ̀n eefa ọkà kan pẹlu àgbò kan, ati ìwọ̀n eefa ọkà tí eniyan bá lágbára pẹlu ọ̀dọ́ aguntan, ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi ìwọ̀n òróró hini kọ̀ọ̀kan ti ìwọ̀n eefa ọkà kọ̀ọ̀kan. +“Nígbà tí ọba bá pèsè ẹbọ ọrẹ àtinúwá, kì báà ṣe ẹbọ sísun, tabi ẹbọ alaafia, ni ọrẹ àtinúwá fún OLUWA tí ó pèsè, wọn yóo ṣí ẹnubodè tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn fún un, yóo sì rú ẹbọ sísun tabi ẹbọ alaafia rẹ̀ bíi ti ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà yóo jáde, wọn óo sì ti ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà náà.” +OLUWA ní, “Yóo máa pèsè ọ̀dọ́ aguntan ọlọ́dún kan tí kò lábàwọ́n fún ẹbọ sísun sí OLUWA lojoojumọ. Láràárọ̀ ni yóo máa pèsè rẹ̀. +Ẹbọ ohun jíjẹ tí yóo máa pèsè pẹlu rẹ̀ láràárọ̀ ni: ìdámẹ́fà eefa ìyẹ̀fun ati ìdámẹ́ta hini òróró tí wọn yóo fi máa po ìyẹ̀fun náà fún ẹbọ ohun jíjẹ fún OLUWA. Èyí ni yóo jẹ́ ìlànà fún ẹbọ sísun ìgbà gbogbo. +Bẹ́ẹ̀ ni wọn óo ṣe máa pèsè aguntan ati ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró láràárọ̀, fún ẹbọ ọrẹ sísun ìgbà gbogbo.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Bí ọba bá fún ọ̀kankan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀bùn lára ilẹ̀ rẹ̀, ilẹ̀ náà di ti àwọn ọmọ rẹ̀, ó di ohun ìní wọn tí wọ́n jogún. +Ṣugbọn bí ó bá fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ ní ẹ̀bùn lára ilẹ̀ rẹ̀, ilẹ̀ náà di tirẹ̀ títí di ọjọ́ tí yóo gba òmìnira; láti ọjọ́ náà ni ilẹ̀ náà yóo ti pada di ti ọba. Àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan ni wọ́n lè jogún ilẹ̀ rẹ̀ títí lae. +Ọba kò gbọdọ̀ gbà ninu ilẹ̀ àwọn ará ìlú láti ni wọ́n lára; ninu ilẹ̀ tirẹ̀ ni kí ó ti pín ogún fún àwọn ọmọ rẹ̀. Kí ẹnikẹ́ni má baà gba ilẹ̀ ọ̀kankan ninu àwọn eniyan mi kúrò lọ́wọ́ wọn.” +Ọkunrin náà bá mú mi gba ọ̀nà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ìlẹ̀kùn, ó bá mú mi lọ sí ibi àwọn yàrá tí ó wà ní apá àríwá ibi mímọ́ náà, tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa, mo sì rí ibìkan níbẹ̀ tí ó wà ní ìpẹ̀kun ní apá ìwọ̀ oòrùn. +Yàrá àbáwọlé ẹnu ọ̀nà yìí ni ọba yóo gbà wọlé, yóo sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ẹnu ọ̀nà. Àwọn alufaa yóo rú ẹbọ sísun ati ti alaafia rẹ̀. Ọba yóo jọ́sìn ní ẹnu ọ̀nà àbájáde, yóo sì jáde; ṣugbọn wọn kò ní ti ìlẹ̀kùn náà títí di ìrọ̀lẹ́. +OLUWA wá sọ fún mi pé, “Ní ibí yìí ni àwọn alufaa yóo ti máa se ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ati ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Ibẹ̀ ni wọn yóo sì ti máa ṣe burẹdi fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí wọn má baà kó wọn jáde wá sí gbọ̀ngàn tí ó wà ní ìta, kí wọn má baà fi ohun mímọ́ kó bá àwọn eniyan.” +Ọkunrin náà bá mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn tí ó wà ní ìta, ó mú mi yíká gbogbo igun mẹrẹẹrin gbọ̀ngàn náà, gbọ̀ngàn kéékèèké kọ̀ọ̀kan sì wà ní igun kọ̀ọ̀kan. +Ní igun mẹrẹẹrin ni àwọn gbọ̀ngàn kéékèèké yìí wà. Ó gùn ní ogoji igbọnwọ (mita 20), ó sì fẹ̀ ní ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 15) àwọn mẹrẹẹrin sì rí bákan náà. +Wọ́n fi òkúta kọ́ igun mẹrẹẹrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yípo. Wọ́n sì kọ́ ibi ìdáná wọn mọ́ ara ògiri. +Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Àwọn ilé ìdáná níbi tí àwọn alufaa tí óo wà níbi pẹpẹ yóo ti máa se ẹran ẹbọ àwọn eniyan mi nìyí.” +Àwọn eniyan yóo jọ́sìn ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé níwájú OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi ati ní ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ oṣù. +Ọ̀dọ́ aguntan mẹfa tí kò lábàwọ́n ati àgbò kan tí kò lábàwọ́n ni ọba yóo fi rú ẹbọ ọrẹ sísun sí OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi. +Ẹbọ ọkà pẹlu àgbò yóo jẹ́ ìwọ̀n eefa kan. Ìwọ̀n ọkà pẹlu iye ọ̀dọ́ aguntan tí ó bá lágbára ni yóo fi rú ẹbọ ọkà pẹlu ọ̀dọ́ aguntan. Ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi òróró hini kọ̀ọ̀kan ti eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan. +Ní ọjọ́ kinni oṣù, yóo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan mẹfa ati àgbò kan tí kò lábàwọ́n rúbọ. +Fún ẹbọ ohun jíjẹ, yóo tọ́jú ìwọ̀n eefa ọkà kan fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, ati eefa ọkà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan ati ìwọ̀n ọkà tí ó bá ti lágbára fún àwọn àgbò, yóo fi hini òróró kọ̀ọ̀kan ti eefa ọkà kọ̀ọ̀kan. +Ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà ni ọba yóo gbà wọlé, ibẹ̀ náà ni yóo sì gbà jáde. +“Ṣugbọn nígbà tí àwọn ará ìlú bá wá siwaju OLUWA ní àkókò àjọ̀dún, ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà apá àríwá wọlé, ẹnu ọ̀nà gúsù ni ó gbọdọ̀ gbà jáde, ẹni tí ó bá sì gba ẹnu ọ̀nà gúsù wọlé, ẹnu ọ̀nà àríwá ni ó gbọdọ̀ gbà jáde. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ẹnu ọ̀nà tó gbà wọlé jáde. Tààrà ni kí olukuluku máa lọ títí yóo fi jáde. +Àwọn Ọba ati Àwọn Àjọ̀dún. +Ọkunrin náà bá mú mi pada wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili, mo sì rí i tí omi kan ń sun láti abẹ́ ìlẹ̀kùn àbájáde ó ń ṣàn lọ sí ìhà ìlà oòrùn, ìhà ìlà oòrùn ni tẹmpili kọjú sí. Omi náà ń ṣàn láti apá gúsù ibi ìlẹ̀kùn àbájáde tí ó wà ni ìhà gúsù pẹpẹ ìrúbọ. +Àwọn apẹja yóo dúró létí òkun láti Engedi títí dé Enegilaimu, ibẹ̀ yóo di ibi tí wọn yóo ti máa na àwọ̀n wọn sá sí. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóo wà níbẹ̀ bí ẹja inú Òkun Ńlá. +Ṣugbọn ibi ẹrọ̀fọ̀ ati àbàtà rẹ̀ kò ní di mímọ́ gaara, iyọ̀ ni yóo wà níbẹ̀. +Oríṣìíríṣìí igi eléso yóo hù ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji odò náà: ewé àwọn igi náà kò ní rọ, bẹ́ẹ̀ ni èso wọn kò ní tán. Lóṣooṣù ni wọn yóo máa so èso tuntun nítorí pé láti inú tẹmpili ni omi rẹ̀ yóo ti máa sun jáde wá. Èso wọn yóo wà fún jíjẹ, ewé wọn yóo sì wà fún ìwòsàn.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Èyí ni yóo jẹ́ ààlà tí ẹ óo fi pín ilẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Josẹfu yóo ní ìpín meji; +ọgbọọgba ni ẹ sì gbọdọ̀ pín in. Mo ti búra pé n óo fún àwọn baba yín, ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ìní yín. +“Bí ààlà ilẹ̀ náà yóo ti lọ nìyí: ní apá àríwá, ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti Òkun Ńlá, yóo gba Etiloni títí dé ẹnubodè Hamati, títí dé ẹnu ibodè Sedadi, +àwọn ìlú Berota, Sibiraimu (tí ó wà ní ààlà Damasku ati Hamati), títí dé Haseri Hatikoni, tí ó wà ní ààlà Haurani. +Ààlà ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ibi òkun títí dé Hasari Enọni, tí ó wà ní ìhà àríwá ààlà Damasku, ààlà ti Hamati yóo wà ní apá àríwá. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìhà àríwá. +“Ní apá ìhà ìlà oòrùn, ààlà náà yóo lọ láti Hasari Enọni tí ó wà láàrin Haurani ati Damasku, ní ẹ̀gbẹ́ odò Jọdani tí ó wà láàrin Gileadi ati ilẹ̀ Israẹli, títí dé òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì lọ títí dé Tamari. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìlà oòrùn. +“Ní ìhà gúsù, ilẹ̀ yín yóo lọ láti Tamari dé àwọn odò Meriba Kadeṣi, títí yóo fi kan odò Ijipti títí lọ dé Òkun-ńlá. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìhà gúsù. +Lẹ́yìn náà ó mú mi gba ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá jáde, ó sì mú mi yípo ní ìta títí tí mo fi dé ẹnu ọ̀nà àbájáde tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Odò kékeré kan ń ṣàn jáde láti ìhà gúsù. +“Ní ìwọ̀ oòrùn, Òkun Ńlá ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín, yóo lọ títí dé òdìkejì ẹnu ọ̀nà Hamati. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn. +“Báyìí ni ẹ óo ṣe pín ilẹ̀ náà láàrin ara yín, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà Israẹli. +Ẹ óo pín in fún ara yín ati fún àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin yín, tí wọ́n sì ti bímọ sí ààrin yín. Ẹ óo kà wọ́n sí ọmọ onílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ óo pín ilẹ̀ fún àwọn náà. +Ààrin ẹ̀yà tí àjèjì náà bá ń gbé ni kí ẹ ti pín ilẹ̀ ìní tirẹ̀ fún un. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Ọkunrin náà lọ sí apá ìhà ìlà oòrùn, ó mú okùn ìwọ̀n kan lọ́wọ́. Ó fi wọn ẹgbẹrun igbọnw��, (mita 450). Ó sì mú mi la odò kan tí ó mù mí dé kókósẹ̀ kọjá. +Ó tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450) mìíràn sí ìsàlẹ̀, ó sì mú mi la odò náà kọjá: odò yìí sì mù mí dé orúnkún. Ọkunrin náà tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450) mìíràn sí ìsàlẹ̀, ó tún mú mi la odò náà kọjá: ó sì mù mí dé ìbàdí. +Nígbà tí ó yá, ó tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450), mìíràn sí ìsàlẹ̀, odò náà jìn ju ohun tí mo lè là kọjá lọ, nítorí pé ó ti kún sí i, ó jìn tó ohun tí eniyan lè lúwẹ̀ẹ́ ninu rẹ̀. Ó kọjá ohun tí eniyan lè là kọjá. +Ọkunrin náà bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o rí nǹkan?” Nígbà náà ni ó mú mi gba etí odò náà pada. +Bí mo ṣe ń pada bọ̀, mo rí ọpọlọpọ igi ní bèbè kinni keji odò náà. +Ó ní, “Omi yìí ń ṣàn lọ sí Araba, ní ìhà ìlà oòrùn, nígbà tí ó bá sì ṣàn wọ inú òkun, omi inú òkun, yóo di omi tí ó mọ́ gaara. +Ọpọlọpọ ohun ẹlẹ́mìí yóo wà ní ibikíbi tí omi náà bá ti ṣàn kọjá. Ẹja yóo pọ̀ ninu rẹ̀; nítorí pé omi yìí ṣàn lọ sí inú òkun, omi tí ó wà níbẹ̀ yóo di mímọ́ gaara, ohunkohun tí ó bá sì wà ní ibi tí odò yìí bá ti ṣàn kọjá yóo yè. +Odò tí Ń Ṣàn láti Tẹmpili. +Orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli nìwọ̀nyí: Ààlà ilẹ̀ náà ní ìhà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etíkun, ó lọ ní apá ọ̀nà Hẹtiloni dé àbáwọ Hamati títí dé Hasari Enọni, tí ó wà ní ààlà Damasku, ní òdìkejì Hamati. Ó lọ láti apá ìlà oòrùn títí dé apá ìwọ̀ oòrùn: Ìpín ti Dani yóo jẹ́ ìpín kan. +Èyí yóo jẹ́ ilẹ̀ fún ibi mímọ́ mi, níbẹ̀ sì ni ìpín ti àwọn alufaa yóo wà, yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ní ìhà àríwá, ní ìwọ̀ oòrùn, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5), ní ìlà oòrùn, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5), òòró rẹ̀ ní ìhà gúsù yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½). Ibi mímọ́ OLUWA yóo wà ní ààrin rẹ̀. +Yóo jẹ́ ti àwọn alufaa tí a yà sọ́tọ̀, àwọn ọmọ Sadoku tí wọ́n pa òfin mi mọ́, tí wọn kò sì ṣáko lọ bí àwọn ọmọ Lefi, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ. +Lọ́tọ̀ ni a óo fún wọn ní ilẹ̀ tiwọn. Yóo jẹ́ ìpín tiwọn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ilẹ̀ mímọ́ jùlọ; yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ ti àwọn ọmọ Lefi. +Àwọn ọmọ Lefi yóo ní ìpínlẹ̀ tiwọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ tí a pín fún àwọn alufaa, òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5). +Wọn kò gbọdọ̀ tà ninu rẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ fi yáwó, wọn kò sì gbọdọ̀ fún ẹlòmíràn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ yìí; nítorí pé mímọ́ ni, ti OLUWA sì ni. +Èyí tí ó kù lára ilẹ̀ náà tí ìbú rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) igbọnwọ (kilomita 2½), tí òòró rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), yóo wà fún lílò àwọn ará ìlú, fún ibùgbé ati ilẹ̀ tí ó yí ìlú ká. Láàrin rẹ̀ ni ìlú yóo wà. +Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ìlú náà yóo gùn ní ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), ati ti ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati ti àríwá ati ti gúsù. +Ilẹ̀ pápá yóo sì wà ní ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ìlú náà, ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan yóo gùn ní igba ó lé aadọta (250) igbọnwọ (mita 125). +Ilẹ̀ tí ó kù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìlà oòrùn, ati ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà. Èso ilẹ̀ náà yóo jẹ́ oúnjẹ fún àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu ìlú. +Àwọn òṣìṣẹ́ ààrin ìlú tí wọ́n bá wá láti inú àwọn ẹ̀yà Israẹli ni yóo máa dá oko níbẹ̀. +Ìpín ti Aṣeri yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Dani, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. +Gbogbo ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½) ní òòró ati ìbú. Èyí ni àròpọ̀ ibi mímọ́ ati ilẹ̀ ti gbogbo ìlú náà. +Ilẹ̀ tí ó kù lápá ọ̀tún ati apá òsì ilẹ̀ mímọ́ náà, ati ti ìlú yóo jẹ́ ti ọba. Ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ibi tí ilẹ̀ mímọ́ pin sí, lọ sí ààlà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ati ibi tí ilẹ̀ mímọ́ náà pin sí, lọ sí ààlà tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ ti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ilẹ̀ mímọ́ ati tẹmpili mímọ́ yóo sì wà láàrin rẹ̀. +Ilẹ̀ àwọn ọmọ Lefi ati ilẹ̀ gbogbo ìlú yóo wà láàrin ilẹ̀ ọba. Ilẹ̀ ọba yóo wà láàrin ilẹ̀ Juda ati ti Bẹnjamini. +Ní ti àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn, Bẹnjamini yóo ní ìpín kan. +Ìpín ti Simeoni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Bẹnjamini, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. +Ìpín kan tí Isakari ní yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Simeoni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. +Ìpín kan ti Sebuluni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Isakari, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. +Ìpín kan ti Gadi yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Sebuluni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. +Lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbègbè Gadi ní ìhà gúsù, ààlà ilẹ̀ náà yóo lọ láti Tamari títí dé ibi àwọn odò Meriba Kadeṣi, títí dé àwọn odò Ijipti, tí ó fi lọ dé Òkun Ńlá. +Ilẹ̀ tí ẹ óo pín láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli nìyí; bẹ́ẹ̀ sì ni ètò bí ẹ óo ṣe pín in fún olukuluku wọn, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +Ìpín ti Nafutali yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Aṣeri, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. +Ìwọ̀nyí ni yóo jẹ́ ẹnubodè àbájáde ìlú náà. Apá ìhà àríwá tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnubodè mẹta. +Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Reubẹni, ẹnubodè Juda ati ẹnubodè Lefi. Orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli ni a fi sọ àwọn ẹnu ọ̀nà ìlú. +Apá ìlà oòrùn tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnu ọ̀nà mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Josẹfu, ẹnubodè Bẹnjamini ati ẹnubodè Dani. +Apá ìhà gúsù tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnu ọ̀nà mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Simeoni, ẹnubodè Isakari ati ẹnubodè Sebuluni. +Apá ìwọ̀ oòrùn tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnubodè mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Gadi, ẹnubodè Aṣeri ati ẹnubodè Nafutali. +Àyíká ìlú náà yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) igbọnwọ (mita 9,000). Orúkọ ìlú náà yóo máa jẹ́, “OLUWA Ń Bẹ Níbí.” +Ìpín ti Manase yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Nafutali, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn, +Ìpín ti Efuraimu yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Manase, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. +Ìpín ti Reubẹni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Efuraimu, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. +Ìpín ti Juda yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Reubẹni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. +Lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Juda ni ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo wà. Ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12.5), òòró rẹ̀ yóo rí bákan náà pẹlu ti àwọn ìpín yòókù láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ibi mímọ́ yóo wà láàrin rẹ̀. +Òòró ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ (kilomita 10). +Pípín Ilẹ̀ Náà láàrin Àwọn Ẹ̀yà Israẹli. +OLUWA ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, mú idà kan tí ó bá mú, lò ó gẹ́gẹ́ bí abẹ ìfárí, kí o fi fá orí ati irùngbọ̀n rẹ. Mú òṣùnwọ̀n tí a fi ń wọn nǹkan kí o fi pín irun tí o bá fá sí ọ̀nà mẹta. +Baba yóo máa pa ọmọ wọn jẹ láàrin yín; ọmọ yóo sì máa pa àwọn baba jẹ. N óo dájọ́ fun yín, n óo fọ́n gbogbo àwọn tí ó kù ninu yín káàkiri igun mẹrẹẹrin ayé. +“Bí mo ti wà láàyè, n óo pa yín run. N kò ní fojú fo ohunkohun, n kò sì ní ṣàánú yín rárá; nítorí ẹ ti fi àwọn nǹkan ẹ̀sìn ìríra ati àṣà burúkú yín sọ ilé mímọ́ mi di aláìmọ́. +Àjàkálẹ̀ àrùn ati ìyàn yóo pa ìdámẹ́ta lára yín, ogun tí yóo máa jà káàkiri yóo pa ìdámẹ́ta yín, n óo fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri gbogbo ayé, n óo sì gbógun tì wọ́n. +“Bẹ́ẹ̀ ni inú mi yóo ṣe máa ru si yín, tí n óo sì bínú si yín títí n óo fi tẹ́ ara mi lọ́rùn. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀ pẹlu owú nígbà tí mo bá bínú si yín tẹ́rùn. +N óo sọ yín di ahoro ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yi yín ká ati lójú gbogbo àwọn tí wọn ń rékọjá lọ. +“Ẹ óo di ẹni ẹ̀sín ati ẹni ẹ̀gàn, ẹni àríkọ́gbọ́n ati ẹni àríbẹ̀rù fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká; nígbà tí mo bá fi ibinu ati ìrúnú dájọ́ fun yín, tí mo sì jẹ yín níyà pẹlu ibinu. +Nígbà tí mo bá ta ọfà burúkú mi si yín: ọfà ìyàn ati ọfà ìparun, tí n óo ta lù yín láti pa yín run, ìyàn óo mú lọpọlọpọ nígbà tí mo bá mú kí oúnjẹ yín tán pátá. +N óo rán ìyàn ati àwọn ẹranko burúkú si yín, wọn óo sì pa yín lọ́mọ. Àjàkálẹ̀ àrùn ati ikú yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin yín, n óo sì jẹ́ kí ogun pa yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Jó ìdámẹ́ta rẹ̀ ninu iná láàrin ìlú, ní ìgbà tí ọjọ́ tí a fi dóti ìlú náà bá parí. Máa fi idà gé ìdámẹ́ta, kí o sì fọ́n ọn káàkiri lẹ́yìn ìlú, fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri sinu afẹ́fẹ́, n óo sì fa idà yọ tẹ̀lé e. +Mú díẹ̀ ninu irun náà kí o dì í sí etí ẹ̀wù rẹ. +Mú díẹ̀ ninu èyí tí o dì sí etí ẹ̀wù, jù ú sinu iná kí ó jóná; iná yóo sì ti ibẹ̀ ṣẹ́ sí gbogbo ilé Israẹli.” +OLUWA Ọlọrun ní: “Jerusalẹmu nìyí. Mo ti fi í sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, mo sì ti fi àwọn agbègbè yí i ká. +Ó ti tàpá sí òfin mi ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ, ó sì ti kọ ìlànà mi sílẹ̀ ju àwọn agbègbè tí ó yí i ká lọ. Wọ́n kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi. +Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun ní nítorí pé rúdurùdu yín ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká lọ, ati pé ẹ kò tẹ̀lé ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká. +Nítorí náà, èmi, OLUWA Ọlọrun fúnra mi, ni mo dójú le yín, n óo sì ṣe ìdájọ́ fun yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè. +Nítorí gbogbo ìwà ìríra yín, n óo ṣe ohun tí n kò ṣe rí si yín, tí n kò sì ní ṣe irú rẹ̀ mọ́ lae. +Isikiẹli Gé Irun Rẹ̀. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA, ati pé kì í ṣe pé mo sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ẹnu lásán pé n óo ṣe wọ́n níbi.’ ” +OLUWA Ọlọrun ní: “Ẹ káwọ́ lérí kí ẹ máa fi ẹsẹ̀ janlẹ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Háà! Ó mà ṣe o!’ Ogun ati ìyàn ati àjàkálẹ̀-àrùn ni yóo pa ilé Israẹli nítorí ìwà ìríra wọn. +Àjàkálẹ̀-àrùn ni yóo pa àwọn tí wọ́n wà lókèèrè; idà yóo pa àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ìyàn yóo sì pa àwọn yòókù tí ogun ati àjàkálẹ̀-àrùn bá dá sí. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn patapata. +Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí òkú wọn bá sùn lọ káàkiri láàrin àwọn ère oriṣa wọn yíká pẹpẹ ìrúbọ wọn, ní gbogbo ibi ìrúbọ ati lórí gbogbo òkè ńlá, lábẹ́ gbogbo igi tútù ati gbogbo igi oaku eléwé tútù; ní gbogbo ibi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí àwọn oriṣa wọn. +Ọwọ́ mi óo tẹ̀ wọ́n; n óo sọ ilẹ̀ wọn di ahoro ati òkítì àlàpà, ní gbogbo ibùgbé wọn, láti ibi aṣálẹ̀ títí dé Ribila. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.” +“Ọmọ eniyan, dojú kọ àwọn òkè Israẹli kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí wọn. +Sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun wí. OLUWA Ọlọrun ń bá àwọn òkè ńláńlá ati àwọn òkè kéékèèké wí! Ó ń sọ fún àwọn ọ̀gbun ati àwọn àfonífojì pé, èmi fúnra mi ni n óo kó ogun wá ba yín, n óo sì pa àwọn ibi ìrúbọ yín run. +Àwọn pẹpẹ ìrúbọ yín yóo di ahoro, a óo fọ́ àwọn pẹpẹ turari yín, n óo sì da òkú yín sílẹ̀ níwájú àwọn oriṣa yín. +N óo da òkú ẹ̀yin ọmọ Israẹli sílẹ̀ níwájú àwọn oriṣa yín, n óo sì fọ́n egungun yín ká níbi pẹpẹ ìrúbọ yín. +Ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, àwọn ìlú yín yóo di ahoro, àwọn ibi ìrúbọ yín yóo di òkítì àlàpà, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn pẹpẹ oriṣa yín yóo di ahoro ati àlàpà. A óo fọ́ àwọn ère oriṣa yín, a óo pa wọ́n run, a óo wó pẹpẹ turari yín, iṣẹ́ yín yóo sì parẹ́. +Òkú yóo sùn lọ bẹẹrẹ láàrin yín, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA. +“ ‘Sibẹsibẹ n óo dá díẹ̀ sí ninu yín; kí ẹ lè ní àwọn tí yóo bọ́ lọ́wọ́ ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nígbà tí ẹ bá fọ́n káàkiri ilé ayé. +Nígbà náà, àwọn tí wọ́n sá àsálà ninu yín yóo ranti mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a bá kó wọn ní ìgbèkùn lọ, nígbà tí mo bá mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn tí ó ń mú wọn kọ̀ mí sílẹ̀ kúrò, tí mo bá sì fọ́ ojú tí wọ́n fi ń ṣe àgbèrè tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn. Ojú ara wọn yóo tì wọ́n nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati nítorí gbogbo ìwà ìríra wọn. +Ọlọrun fi Ìbọ̀rìṣà Gégùn-ún. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +Ọjọ́ pé. Ẹ wò ó! Ọjọ́ ti pé! Ìparun yín ti dé. Ìwà àìṣẹ̀tọ́ ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìgbéraga ń rúwé. +Ìwà ipá hù, ó dàgbà, ó di ọ̀pá ìwà ibi; bí ẹ ti pọ̀ tó, ẹ kò ní ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan, àtẹ̀yin ati àwọn ohun ìní yín, ati ọrọ̀ yín ati ògo yín. +Àkókò tó; ọjọ́ náà sì ti dé tán, kí ẹni tí ń ra nǹkan má ṣe yọ̀; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹni tí ń tà má sì banújẹ́, nítorí ibinu ti dé sórí gbogbo wọn. +Ẹni tí ń tà kò ní sí láyé láti pada síbi ohun tí ó tà ní ìgbà ayé ẹni tí ó rà á. Nítorí ibinu ti dé sórí gbogbo wọn. Kò sì ní yipada, bẹ́ẹ̀ ni nítorí ẹ̀ṣẹ̀ olukuluku, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní sí láàyè. +Wọn óo fọn fèrè ogun, wọn óo múra ogun, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò ní jáde lọ sójú ogun nítorí ibinu mi ti dé sórí gbogbo wọn. +Ogun ń bẹ lóde; àjàkálẹ̀-àrùn ati ìyàn wà ninu ilé. Ẹni tí ó bá wà lóko yóo kú ikú ogun. Ìyàn ati àjàkálẹ̀-àrùn yóo pa ẹni tí ó bá wà ninu ìlú. +Bí àwọn kan bá kù, tí wọn sá àsálà, wọn yóo dàbí àdàbà àfonífojì lórí àwọn òkè. Gbogbo wọn yóo máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn olukuluku yóo máa dárò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. +Ọwọ́ gbogbo wọ́n yóo rọ; orúnkún wọn kò ní lágbára. +Wọn óo wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ìpayà óo sì bá wọn. Ojú óo ti gbogbo wọn; gbogbo wọn óo sì di apárí. +Wọ́n óo fọ́n fadaka wọn dà sílẹ̀ láàrin ìgboro. Wúrà wọn yóo sì dàbí ohun àìmọ́. Fadaka ati wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́jọ́ ibinu OLUWA. Kò ní lè tẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní lè jẹ ẹ́ yó. Nítorí pé wúrà ati fadaka ló mú wọn dẹ́ṣẹ̀. +“Ìwọ ọmọ eniyan, ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun sọ nípa ilẹ̀ Israẹli ni pé: òpin ti dé. Òpin dé sórí igun mẹrẹẹrin ilẹ̀ náà. +Wọ́n ń lo ohun ọ̀ṣọ́ wọn dáradára fún ògo asán; òun ni wọ́n fi ń ṣe àwọn ère ati oriṣa wọn, àwọn ohun ìríra tí wọn ń bọ. Nítorí náà, OLUWA óo sọ wọ́n di ohun àìmọ́ fún wọn. +OLUWA ní, “N óo sọ wọ́n di ìjẹ fún àwọn àjèjì, n óo sì fi wọ́n ṣe ìkógun fún àwọn eniyan burúkú ilé ayé. Wọn óo sọ wọ́n di ohun eléèérí. +N óo mójú kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí wọ́n lè sọ ibi dídára mi di eléèérí. Àwọn ọlọ́ṣà yóo wọnú rẹ̀, wọn yóo sì sọ ọ́ di eléèérí. +“Nítorí pé ìpànìyàn kún ilẹ̀ náà, ìlú wọn sì kún fún ìwà ipá. +N óo kó àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n burú jùlọ wá, wọn óo wá gba ilé wọn. N óo fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára wọn, wọn yóo sì sọ àwọn ibi mímọ́ wọn di eléèérí. +Nígbà tí ìrora bá dé, wọn yóo máa wá alaafia, ṣugbọn wọn kò ní rí i. +Àjálù yóo máa yí lu àjálù, ọ̀rọ̀ àhesọ yóo máa gorí ara wọn. Wọn yóo máa wo ojú wolii fún ìran ṣugbọn kò ní sí, alufaa kò ní náání òfin mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ìmọ̀ràn mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà. +Ọba yóo máa ṣọ̀fọ̀; àwọn olórí yóo sì wà ninu ìdààmú; ọwọ́ àwọn eniyan yóo sì máa gbọ̀n nítorí ìpayà. N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn fún wọn; n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ bí àwọn náà tí ń dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +“Òpin ti dé ba yín báyìí, n óo bínú si yín, n óo da yín lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwà yín; n óo sì jẹ yín níyà nítorí gbogbo ìwà ìríra yín. +N kò ní fojú fo ọ̀rọ̀ yín, n kò sì ní ṣàánú yín. Ṣugbọn n óo jẹ yín níyà fún gbogbo ìwà yín níwọ̀n ìgbà tí ohun ìríra ṣì wà láàrin yín. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.” +OLUWA Ọlọrun ní: “Àjálù dé! Ẹ wò ó! Àjálù ń ré lu àjálù. +Òpin dé! Òpin ti dé; ó ti dé ba yín. +Ẹ wò ó! Ó ti dé. Ìparun ti dé ba yín, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ yìí. Àkókò tó, ọjọ́ ti súnmọ́lé, ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀, tí kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí àwọn òkè. +“Ó yá tí n óo bínú si yín, tí inú mi óo ru si yín gidi. N óo da yín lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwà yín, n óo sì jẹ yín níyà nítorí gbogbo ìwà ìríra yín. +N kò ní fojú fo ọ̀rọ̀ yín, n kò ní ṣàánú yín. N óo jẹ yín níyà gẹ́gẹ́ bí ìwà yín, níwọ̀n ìgbà tí ohun ìríra ṣì wà láàrin yín. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi OLUWA, ni mò ń jẹ yín níyà.” +Òpin ti dé Tán fún Israẹli. +Ní ọjọ́ karun-un, oṣù kẹfa ọdún kẹfa tí a ti wà ní ìgbèkùn, bí mo ti jókòó ninu ilé mi, tí àwọn àgbààgbà Juda sì jókòó níwájú mi, agbára OLUWA Ọlọrun bà lé mi níbẹ̀. +Mo bá wọlé láti wo ohun tí ó wà níbẹ̀. Mo rí àwòrán oríṣìíríṣìí kòkòrò ati ti ẹranko, tí ń rí ni lára, ati gbogbo oriṣa àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n yà sí ara ògiri yíká. +Mo sì rí aadọrin ninu àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dúró níwájú àwọn oriṣa wọnyi, Jaasanaya ọmọ Ṣafani dúró láàrin wọn. Olukuluku mú ohun tí ó fi ń sun turari lọ́wọ́, èéfín turari sì ń fẹ́ lọ sókè. +OLUWA tún bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Israẹli ń ṣe ninu òkùnkùn? Ṣé o rí ohun tí olukuluku ń ṣe ninu yàrá tí ó kún fún àwòrán ère oriṣa? Wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA kò rí wa, ó ti kọ ilẹ̀ wa sílẹ̀.’ ” +Ó tún sọ fún mi pé, “N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn tí ó jù báyìí lọ tí wọn ń ṣe hàn ọ́.” +Nígbà náà ni ó mú mi lọ sí ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà àríwá ilé OLUWA. Wò ó, mo rí àwọn obinrin kan níbẹ̀, tí wọ́n jókòó, tí wọn ń sunkún nítorí Tamusi. +Ó sì bi mí pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? O óo tún rí nǹkan ìríra tí ó ju èyí lọ.” +Ó mú mi wọ inú gbọ̀ngàn tí ó wà ninu ilé OLUWA; mo bá rí àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà tẹmpili ilé OLUWA, láàrin ìloro ati pẹpẹ. Wọ́n kẹ̀yìn sí tẹmpili OLUWA, wọ́n sì kọjú sí ìlà oòrùn. Wọ́n ń foríbalẹ̀ wọ́n ń bọ oòrùn. +Ó bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? Ṣé nǹkan ìríra tí àwọn ọmọ ilé Juda ń ṣe níhìn-ín kò jọ wọ́n lójú ni wọ́n ṣe mú kí ìwà ìkà kún ilẹ̀ yìí, tí wọn ń mú mi bínú sí i? Wò bí wọ́n ti ń tàbùkù mi, tí wọn ń fín mi níràn. +Nítorí náà, n óo bínú sí wọn, n kò ní fojú fo iṣẹ́ wọn, n kò sì ní ṣàánú wọn. Wọ́n ìbáà máa kígbe sí mi létí, n kò ní dá wọn lóhùn.” +Nígbà tí mo wò, mo rí nǹkankan tí ó dàbí eniyan. Láti ibi tí ó dàbí ìbàdí rẹ̀ dé ilẹ̀ jẹ́ iná, ibi ìbàdí rẹ̀ sókè ń kọ mànàmànà bí idẹ dídán. +Ó na nǹkankan tí ó dàbí ọwọ́, ó fi gbá ìdí irun orí mi mú, ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede meji ọ̀run ati ayé, ó gbé mi lọ sí Jerusalẹmu, ninu ìran Ọlọrun, ó gbé mi sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá gbọ̀ngàn ti inú tí ó kọjú sí ìhà àríwá, níbi tí wọ́n gbé ère tí ń múni jowú sí. +Mo rí ìfarahàn ògo Ọlọrun Israẹli níbẹ̀ bí mo ti rí i lákọ̀ọ́kọ́ ní àfonífojì. +Ó bá sọ fún mi, pé: “Ọmọ eniyan, gbójú sókè sí apá àríwá.” Mo bá gbójú sókè sí apá àríwá. Wò ó! Mo rí ère kan tí ń múni jowú ní ìhà àríwá ẹnu ọ̀nà pẹpẹ ìrúbọ. +OLUWA sọ fún mi pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe? Ṣé o rí nǹkan ìríra ńlá tí àwọn ọmọ Israẹli ń ṣe níhìn-ín láti lé mi jìnnà sí ilé mímọ́ mi? N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn hàn ọ́.” +OLUWA bá tún gbé mi lọ sí ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn, nígbà tí mo wò yíká, mo rí ihò kan lára ògiri. +Ó bá sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, gbẹ́ ara ògiri yìí.” Nígbà tí mo gbẹ́ ara ògiri náà, mo rí ìlẹ̀kùn kan! +Ó bá sọ fún mi pé, “Wọlé kí o rí nǹkan ìríra tí wọn ń ṣe níbẹ̀.” +Ìran Keji tí Ọlọrun Fi Han Isikiẹli. +Lẹ́yìn náà, Ọlọrun kígbe sí mi létí, ó ní, “Ẹ súnmọ́bí, ẹ̀yin tí ẹ óo pa ìlú yìí run, kí olukuluku mú nǹkan ìjà rẹ̀ lọ́wọ́.” +N kò ní mójú fo ọ̀rọ̀ wọn, n kò sì ní ṣàánú wọn. N óo da ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn lé wọn lórí.” +Mo bá gbọ́ tí ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó sì ní àpótí ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́, ń jábọ̀ pé, “Mo ti ṣe bí o ti pàṣẹ fún mi.” +Wò ó! Mo bá rí àwọn ọkunrin mẹfa kan tí wọn ń bọ̀ láti ẹnu ọ̀nà òkè tí ó kọjú sí ìhà àríwá. Olukuluku mú ohun ìjà tí ó fẹ́ fi pa eniyan lọ́wọ́. Ọkunrin kan wà láàrin wọn tí ó wọ aṣọ funfun, ó sì ní àpótí ìkọ̀wé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́. Wọ́n wọlé, wọ́n dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ. +Ògo Ọlọrun Israẹli ti gbéra kúrò lórí àwọn Kerubu tí ó wà, ó dúró sí àbáwọlé. Ó ké sí ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà, tí ó sì ní àpótí ìkọ̀wé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́. +OLUWA bá sọ fún un pé, “Lọ káàkiri ìlú Jerusalẹmu, kí o fi àmì sí iwájú àwọn eniyan tí wọ́n bá ń kẹ́dùn, tí gbogbo nǹkan ìríra tí àwọn eniyan ń ṣe láàrin ìlú náà sì dùn wọ́n dọ́kàn.” +Mo sì gbọ́ tí ó wí fún àwọn yòókù pé: “Ẹ lọ káàkiri ìlú yìí, kí ẹ máa pa àwọn eniyan. Ẹ kò gbọdọ̀ dá ẹnikẹ́ni sí, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú ẹnikẹ́ni. +Ẹ pa àwọn àgbàlagbà patapata, ati àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin pẹlu, ati àwọn ọmọde ati àwọn obinrin. Ṣugbọn ẹ má fọwọ́ kan ẹnikẹ́ni tí àmì bá wà níwájú rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́ mi.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà níwájú ilé OLUWA. +Lẹ́yìn náà, Ọlọrun sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ ilé náà di aláìmọ́, ẹ kó òkú eniyan kún gbọ̀ngàn rẹ̀, kí ẹ sì bọ́ síta.” Wọ́n bá bẹ́ sí ìgboro, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn eniyan láàrin ìlú. +Bí wọ́n ti ń pa àwọn eniyan, tí èmi nìkan dá dúró, mo dojúbolẹ̀, mo kígbe. Mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o óo pa gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Israẹli nítorí pé ò ń bínú sí Jerusalẹmu ni?” +Ó dá mi lóhùn, ó ní: “Ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli ati ti Juda pọ̀jù. Ilẹ̀ náà kún fún ìpànìyàn, ìlú yìí sì kún fún ìwà àìṣẹ̀tọ́. Wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA ti kọ ilẹ̀ yìí sílẹ̀, kò sì rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ninu rẹ̀.’ +Wọ́n Jẹ Jerusalẹmu Níyà. +Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Pasia, kí àsọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wolii Jeremaya lè ṣẹ, OLUWA fi sí Kirusi ọba lọ́kàn láti kéde yíká gbogbo ìjọba rẹ̀ ati láti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé: +ọgbọ̀n àwokòtò wúrà,ẹgbaa ó lé irinwo ati mẹ́wàá (2,410) àwo fadaka kéékèèké,ẹgbẹrun (1,000) oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn. +Àpapọ̀ àwọn ohun èlò wúrà ati fadaka yìí jẹ́ ẹẹdẹgbaata ó lé irinwo (5,400). Ṣeṣibasari kó wọn lọ́wọ́ bí àwọn tí wọn kúrò ní oko ẹrú Babiloni ti ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. +“Èmi Kirusi, ọba Pasia kéde pé: OLUWA Ọlọrun ọ̀run ti fi gbogbo ìjọba ayé fún mi, ó sì ti pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé kan fún òun ní Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda. +Kí Ọlọrun wà pẹlu àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan rẹ̀. Ẹ lọ sí Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda, kí ẹ tún ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli kọ́, nítorí òun ni Ọlọrun tí wọn ń sìn ní Jerusalẹmu. +Ní gbogbo ibi tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn eniyan rẹ̀ ń gbé, kí àwọn aládùúgbò wọn fi fadaka, wúrà, dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn ta wọ́n lọ́rẹ, yàtọ̀ sí ọrẹ àtinúwá fún ilé Ọlọrun.” +Àwọn olórí ninu ìdílé ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Bẹnjamini, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi sì dìde, pẹlu àwọn tí Ọlọrun ti fi sí lọ́kàn láti tún ilé OLUWA tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́. +Àwọn aládùúgbò wọn fi ohun èlò fadaka ati ti wúrà, ati dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ràn wọ́n lọ́wọ́, yàtọ̀ sí àwọn ọrẹ àtinúwá. +Kirusi ọba náà kó àwọn ohun èlò inú ilé OLUWA jáde, tí Nebukadinesari kó wá sinu àwọn ilé oriṣa rẹ̀, láti Jerusalẹmu. +Kirusi ọba fún Mitiredati, akápò ìjọba rẹ̀ ní àṣẹ láti kó wọn síta, ó sì kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Ṣeṣibasari, olórí ẹ̀yà Juda. +Iye àwọn nǹkan náà nìyí:Ẹgbẹrun kan (1,000) àwo wúrà,ẹgbẹrun kan (1,000) àwo fadaka,àwo turari mọkandinlọgbọn; +Kirusi Ọba Pàṣẹ pé kí Àwọn Juu Pada. +Bí Ẹsira ti ń gbadura, tí ó ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ń sọkún, tí ó sì dojúbolẹ̀ níwájú ilé Ọlọrun, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí dúró yí i ká, tọmọde, tàgbà, tọkunrin, tobinrin. Àwọn náà ń sọkún gan-an. +Ẹsira, alufaa, bá dìde, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣẹ̀ níti pé ẹ fẹ́ obinrin àjèjì, ẹ sì ti mú kí ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli pọ̀ sí i. +Nítorí náà ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín, kí ẹ sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan náà ati kúrò lọ́dọ̀ àwọn obinrin àjèjì.” +Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè, wọ́n dáhùn pé, “Òtítọ́ ni o sọ, bí o ti wí ni a gbọdọ̀ ṣe. +Ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi pọ̀, ati pé àkókò òjò nìyí; a kò lè dúró ní gbangba báyìí. Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ohun tí a lè parí ní ọjọ́ kan tabi ọjọ́ meji, nítorí ohun tí a ṣe yìí, a ti ṣẹ̀ gan-an +Jẹ́ kí àwọn olórí wa dúró fún gbogbo àwùjọ yìí, kí wọ́n dá ọjọ́ tí àwọn tí wọ́n fẹ́ iyawo àjèjì ninu àwọn ìlú wa yóo wá, pẹlu àwọn àgbààgbà, ati àwọn adájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ibinu Ọlọrun lórí ọ̀rọ̀ yìí yóo fi kúrò lórí wa.” +Gbogbo wọn ni wọ́n faramọ́ ìmọ̀ràn yìí àfi Jonatani, ọmọ Asaheli ati Jahiseaya, ọmọ Tikifa. Àwọn ọmọ Lefi meji: Meṣulamu ati Ṣabetai náà faramọ́ àwọn tí wọ́n lòdì sí i. +Àwọn tí wọ́n pada ti oko ẹrú dé gba ìmọ̀ràn yìí. Nítorí náà, Ẹsira alufaa yan àwọn olórí ninu ìdílé wọn, wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀. Ní ọjọ́ kinni oṣù kẹwaa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí. +Nígbà tí yóo fi di ọjọ́ kinni oṣù kinni, wọ́n ti parí ìwádìí lórí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì. +Orúkọ àwọn alufaa tí wọ́n fẹ́ àwọn obinrin àjèjì nìwọ̀nyí:Ninu ìdílé Jeṣua ọmọ Josadaki ati àwọn arakunrin rẹ̀: Maaseaya ati Elieseri, Jaribu, ati Gedalaya. +Wọ́n ṣe ìpinnu láti kọ àwọn aya wọn sílẹ̀, wọ́n sì fi àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn. +Ṣekanaya, ọmọ Jehieli, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Elamu bá sọ fún Ẹsira pé: “A ti hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí Ọlọrun wa, nítorí a ti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ẹ̀yà tí wọ́n yí wa ká, sibẹsibẹ, ìrètí ń bẹ fún àwọn ọmọ Israẹli. +Ninu ìdílé Imeri: Hanani, ati Sebadaya. +Ninu ìdílé Harimu: Maaseaya, Elija, Ṣemaaya, Jehieli, ati Usaya. +Ninu ìdílé Paṣuri: Elioenai, Maaseaya, Iṣimaeli, Netaneli, Josabadi, ati Elasa. +Orúkọ àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n fẹ́ àwọn obinrin àjèjì nìwọ̀nyí:Josabadi, Ṣimei, Kelaya, (tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Kelita), Petahaya, Juda, ati Elieseri. +Ninu àwọn akọrin, Eliaṣibu nìkan ni ó fẹ́ obinrin àjèjì.Orúkọ àwọn aṣọ́nà tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì nìwọ̀nyí:Ṣalumu, Telemu, ati Uri. +Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì nìwọ̀nyí:Ninu ìdílé Paroṣi: Ramaya, Isaya, ati Malikija; Mijamini, Eleasari, Haṣabaya ati Benaaya. +Ninu ìdílé Elamu: Matanaya, Sakaraya, ati Jehieli; Abidi, Jeremotu, ati Elija. +Ninu ìdílé Satu: Elioenai, Eliaṣibu, ati Matanaya, Jeremotu, Sabadi, ati Asisa. +Ninu ìdílé Bebai: Jehohanani, Hananaya, Sabai, ati Atilai. +Ninu ìdílé Bani: Meṣulamu, Maluki, ati Adaaya, Jaṣubu, Ṣeali, ati Jeremotu. +Nítorí náà, jẹ́ kí á bá Ọlọrun wa dá majẹmu pé a óo lé àwọn obinrin àjèjì wọnyi lọ pẹlu àwọn ọmọ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwọ, oluwa mi, ati àwọn tí wọ́n bẹ̀rù òfin Ọlọrun wa wí, kí á ṣe é bí òfin ti wí. +Ninu ìdílé Pahati Moabu: Adina, Kelali, ati Benaaya; Maaseaya, Matanaya, ati Besaleli; Binui, ati Manase. +Ninu ìdílé Harimu: Elieseri, Iṣija, ati Malikija; Ṣemaaya, ati Ṣimeoni. +Bẹnjamini, Maluki ati Ṣemaraya. +Ninu ìdílé Haṣumu: Matenai, Matata, ati Sabadi; Elifeleti, Jeremai, Manase, ati Ṣimei. +Ninu ìdílé Bani: Maadai, Amramu, ati Ueli; +Benaaya, Bedeaya, ati Keluhi; +Faniya, Meremoti, ati Eliaṣibu, +Matanaya, Matenai ati Jaasu. +Ninu ìdílé Binui: Ṣimei, +Ṣelemaya, Natani, ati Adaaya, +Ọwọ́ rẹ ni ọ̀rọ̀ yí wà; dìde nílẹ̀ kí o ṣe é. A wà lẹ́yìn rẹ, nítorí náà ṣe ọkàn gírí.” +Makinadebai, Ṣaṣai ati Ṣarai, +Asareli, Ṣelemaya, ati Ṣemaraya, +Ṣalumu, Amaraya, ati Josẹfu. +Ninu ìdílé Nebo: Jeieli, Matitaya, Sabadi, Sebina, Jadai, Joẹli, ati Benaaya. +Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì ni wọ́n kọ àwọn aya wọn sílẹ̀ tọmọtọmọ. +Ẹsira bá dìde nílẹ̀, ó wí fún gbogbo àwọn olórí alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n búra pé wọn yóo ṣe gẹ́gẹ́ bí Ṣekanaya ti sọ, wọ́n sì búra. +Nígbà náà ni Ẹsira kúrò níwájú ilé Ọlọrun, ó lọ sí yàrá Jehohanani, ọmọ Eliaṣibu, ibẹ̀ ni ó sùn ní alẹ́ ọjọ́ náà. Kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu nítorí pé ó ń banújẹ́ nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé. +Wọ́n kéde jákèjádò Juda ati Jerusalẹmu pé kí gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé péjọ sí Jerusalẹmu. +Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ àwọn olórí ati àwọn àgbààgbà, ẹnikẹ́ni tí kò bá farahàn títí ọjọ́ mẹta, yóo pàdánù àwọn ohun ìní rẹ̀, a óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé. +Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kẹta yóo fi ṣú, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọn ń gbé agbègbè Bẹnjamini ati Juda ni wọ́n wá sí Jerusalẹmu. Ní ogúnjọ́ oṣù kẹsan-an ni gbogbo wọn péjọ, wọn jókòó sí ìta gbangba níwájú ilé Ọlọrun. Gbogbo wọn ń gbọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n pè wọ́n fún ati nítorí òjò tí ń rọ̀. +Ètò láti fi Òpin sí Igbeyawo láàrin àwọn Juu ati àwọn tí Wọn kì í ṣe Juu. +Àwọn ọmọ Juda wọnyi ni wọ́n pada dé láti oko ẹrú ní Babiloni, níbi tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, kó wọn lẹ́rú lọ. Wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati ilẹ̀ Juda, olukuluku pada sí ìlú rẹ̀. +Àwọn ọmọ Bani jẹ́ ẹgbẹta ó lé mejilelogoji (642) +Àwọn ọmọ Bebai jẹ́ ẹgbaata ó lé mẹtalelogun (623) +Àwọn ọmọ Asigadi jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mejilelogun (1,222) +Àwọn ọmọ Adonikamu jẹ́ ẹgbẹta ó lé mẹrindinlaadọrin (666) +Àwọn ọmọ Bigifai jẹ́ ẹgbaa ó lé mẹrindinlọgọta (2,056) +Àwọn ọmọ Adini jẹ́ irinwo ó lé mẹrinlelaadọta (454) +Àwọn ọmọ Ateri láti inú ìran Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un +Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹtalelogun (323) +Àwọn ọmọ Jora jẹ́ aadọfa ó lé meji (112) +Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223) +Àwọn olórí wọn ni: Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Seraaya, Reelaya, Modekai, Biliṣani, Misipa, Bigifai, Rehumu ati Baana.Iye àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n pada láti oko ẹrú ní ìdílé ìdílé nìyí: +Àwọn ọmọ Gibari jẹ́ marundinlọgọrun-un +Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹtalelọgọfa (123) +Àwọn eniyan Netofa jẹ́ mẹrindinlọgọta +Àwọn eniyan Anatoti jẹ́ mejidinlaadoje (128) +Àwọn ọmọ Asimafeti jẹ́ mejilelogoji +Àwọn ọmọ Kiriati Jearimu; Kefira ati Beeroti jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹtalelogoji (743) +Àwọn ọmọ Rama ati Geba jẹ́ ẹgbẹta ó lé mọkanlelogun (621) +Àwọn ọmọ Mikimaṣi jẹ́ mejilelọgọfa (122) +Àwọn eniyan Bẹtẹli ati Ai jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223) +Àwọn ọmọ Nebo jẹ́ mejilelaadọta +Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa lé mejilelaadọsan-an (2,172) +Àwọn ọmọ Magibiṣi jẹ́ mẹrindinlọgọjọ (156) +Àwọn ọmọ Elamu keji jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254) +Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ọọdunrun ó lé ogún (320) +Àwọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹẹdọgbọn (725) +Àwọn ọmọ Jẹriko jẹ́ ojilelọọdunrun ó lé marun-un (345) +Àwọn ọmọ Senaa jẹ́ egbejidinlogun ó lé ọgbọ̀n (3,630) +Iye àwọn alufaa tí wọ́n pada dé láti, oko ẹrú wọn nìwọ̀nyí:Àwọn ọmọ Jedaaya láti inú ìdílé Jeṣua jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹtalelaadọrin (973) +Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052) +Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247) +Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017) +Àwọn ọmọ Ṣefataya jẹ́ ọọdunrun ó lé mejilelaadọrin (372) +Iye àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú nìwọ̀nyí:Àwọn ọmọ Jeṣua ati Kadimieli láti inú ìran Hodafaya jẹ́ mẹrinlelaadọrin +Àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ní tẹmpili jẹ́ mejidinlaadoje (128) +Iye àwọn ọmọ àwọn aṣọ́nà:àwọn ọmọ Ṣalumu ati àwọn ọmọ Ateri, àwọn ọmọ Talimoni ati àwọn ọmọ Akubu; àwọn ọmọ Hatita ati àwọn ọmọ Ṣobai jẹ́ mọkandínlogoje (139) +Àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili nìwọ̀nyí:àwọn ọmọ Siha, àwọn ọmọ Hasufa ati àwọn ọmọ Tabaoti; +àwọn ọmọ Kerosi, àwọn ọmọ Siaha ati àwọn ọmọ Padoni; +àwọn ọmọ Lebana, àwọn ọmọ Hagaba ati àwọn ọmọ Akubu; +àwọn ọmọ Hagabu, àwọn ọmọ Ṣamlai ati àwọn ọmọ Hanani; +àwọn ọmọ Gideli, àwọn ọmọ Gahari ati àwọn ọmọ Reaaya; +àwọn ọmọ Resini, àwọn ọmọ Nekoda ati àwọn ọmọ Gasamu; +àwọn ọmọ Usa, àwọn ọmọ Pasea, ati àwọn ọmọ Besai; +Àwọn ọmọ Ara jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin lé marundinlọgọrin (775) +àwọn ọmọ Asina, àwọn ọmọ Meuni, ati àwọn ọmọ Nefisimu; +àwọn ọmọ Bakibuki, àwọn ọmọ Akufa, àwọn ọmọ Hahuri, +àwọn ọmọ Basiluti, àwọn ọmọ Mehida, ati àwọn ọmọ Haṣa, +àwọn ọmọ Bakosi, àwọn ọmọ Sisera, ati àwọn ọmọ Tema, +àwọn ọmọ Nesaya ati àwọn ọmọ Hatifa. +Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni nìyí:àwọn ọmọ Sotai, àwọn ọmọ Hasofereti, ati àwọn ọmọ Peruda; +àwọn ọmọ Jaala, àwọn ọmọ Dakoni, ati àwọn ọmọ Gideli; +àwọn ọmọ Ṣefataya ati àwọn ọmọ Hatili, àwọn ọmọ Pokereti Hasebaimu ati àwọn ọmọ Ami. +Àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili ati àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni jẹ́ irinwo ó dín mẹjọ (392). +Àwọn kan wá láti Teli Mela, Teli Hariṣa, Kerubu, Adani ati Imeri tí wọn kò mọ ìdílé baba wọn tabi ìran wọn, yálà wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli àwọn nìwọ̀nyí: +Àwọn ọmọ Pahati Moabu láti inú ìran Jeṣua ati Joabu jẹ́ ẹgbẹrinla lé mejila (2,812) +Àwọn ọmọ Delaaya, àwọn ọmọ Tobaya, ati àwọn ọmọ Nekoda. Gbogbo wọn jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín mẹjọ (652). +Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ alufaa ninu wọn nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Habaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí ó fẹ́ aya ninu ìdílé Basilai ará Gileadi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ àna rẹ̀ pe àwọn ọmọ rẹ̀). +Wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí a kọ ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn wọn kò rí i. Nítorí náà a kà wọ́n kún aláìmọ́, a sì yọ wọ́n kúrò ninu iṣẹ́ alufaa. +Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn oúnjẹ mímọ́ jùlọ, títí tí wọn yóo fi rí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu láti wádìí lọ́wọ́ OLUWA. +Àpapọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹgbaa, ó lé ọtalelọọdunrun (42,360). +Láìka àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó lé ojilelọọdunrun ó dín mẹta (7,337). Wọ́n sì tún ní igba (200) akọrin lọkunrin, ati lobinrin. +Àwọn ohun ọ̀sìn tí wọ́n kó bọ̀ nìwọ̀nyí: ẹṣin wọn jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹrindinlogoji (736) akọ mààlúù wọn jẹ́ igba ó lé marundinlaadọta (245) +Ràkúnmí wọn jẹ́ irinwo ó lé marundinlogoji (435), kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbaata ó lé okoolelẹẹdẹgbẹrin (6,720). +Nígbà tí wọ́n dé ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, díẹ̀ ninu àwọn olórí ìdílé náà fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ láti tún ilé Ọlọrun kọ́ sí ààyè rẹ̀. +Wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí agbára wọn ti tó. Wọ́n fi ọọdunrun ó lé mejila (312) kilogiramu wúrà ẹgbẹsan (1,800) kilogiramu fadaka ati ọgọrun-un (100) ẹ̀wù alufaa, ṣe ẹ̀bùn fún ilé OLUWA. +Àwọn ọmọ Elamu jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254) +Àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn kan ninu àwọn eniyan náà ń gbé Jerusalẹmu ati agbègbè rẹ̀. Àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili ń gbé àwọn ìlú tí ó wà nítòsí wọn, àwọn ọmọ Israẹli yòókù sì ń gbé àwọn ìlú wọn. +Àwọn ọmọ Satu jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé marundinlaadọta (945) +Àwọn ọmọ Sakai jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé ọgọta (760) +Àwọn tí Wọ́n Pada ti Oko Ẹrú Dé. +Ní oṣù keje tí àwọn ọmọ Israẹli ti pada sí ìlú wọn, gbogbo wọn péjọ sí Jerusalẹmu. +Nígbà tí àwọn mọlémọlé bẹ̀rẹ̀ sí fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀, àwọn alufaa gbé ẹ̀wù wọn wọ̀, wọ́n dúró pẹlu fèrè lọ́wọ́ wọn. Ìdílé Asafu, ẹ̀yà Lefi, ń lu kimbali wọn, wọ́n fí ń yin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi, ọba Israẹli, ti ṣe. +Pẹlu orin ìyìn ati ìdúpẹ́ wọ́n ń kọrin sí OLUWA pẹlu ègbè rẹ̀ pé,“OLUWA ṣeun,ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí lae.”Gbogbo àwọn eniyan hó ìhó ìyìn sí OLUWA, nítorí pé wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀. +Ṣugbọn ọpọlọpọ àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi, ati àwọn olórí ìdílé, àwọn àgbàlagbà tí wọ́n gbọ́njú mọ ilé OLUWA ti tẹ́lẹ̀ sọkún, wọ́n kígbe sókè nígbà tí wọ́n rí bí a ti ń fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA náà lélẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mìíràn hó fún ayọ̀. +Kò sí ẹni tí ó lè mọ ìyàtọ̀ láàrin ariwo ẹkún ati ti ayọ̀ nítorí pé, gbogbo wọn ń kígbe sókè, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan sì gbọ́ igbe wọn ní ọ̀nà jíjìn réré. +Jeṣua, ọmọ Josadaki pẹlu àwọn alufaa ẹgbẹ́ rẹ̀ ati Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, pẹlu àwọn ìbátan rẹ̀ tún pẹpẹ Ọlọrun Israẹli kọ́, kí wọ́n baà lè máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin Mose, eniyan Ọlọrun. +Wọ́n tẹ́ pẹpẹ náà sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn eniyan ibẹ̀; wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí rẹ̀ ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́. +Wọ́n ṣe àjọ̀dún Àgọ́ Àjọ, wọ́n rú ìwọ̀n ẹbọ sísun tí a ti ṣe ìlànà sílẹ̀ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. +Lẹ́yìn náà, wọ́n rú àwọn ẹbọ wọnyi: ẹbọ àtìgbà-dégbà, ẹbọ oṣù titun, gbogbo ẹbọ ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati ti àwọn tí wọ́n bá fẹ́ rú ẹbọ àtinúwá sí OLUWA. +Láti ọjọ́ kinni oṣù keje ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ sísun sí OLUWA bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, wọn kò tíì fi ìpìlẹ̀ tẹmpili lélẹ̀. +Wọ́n fi owó sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń gbẹ́ òkúta ati fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà. Wọ́n fún àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Tire ní oúnjẹ, ohun mímu, ati òróró; wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún igi kedari láti ilẹ̀ Lẹbanoni. Wọ́n ní kí wọ́n kó àwọn igi náà wá sí Jọpa ní etí òkun fún wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Kirusi, ọba Pasia pa. +Ní oṣù keji ọdún keji tí wọ́n dé sí ilé Ọlọrun ní Jerusalẹmu ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, pẹlu àwọn arakunrin wọn yòókù, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n yan àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ti tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, láti máa bojútó iṣẹ́ ilé OLUWA. +Jeṣua ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu àwọn ìbátan rẹ̀, ati Kadimieli pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Juda ń ṣe alabojuto àwọn tí wọn ń kọ́ ilé Ọlọrun pẹlu àwọn ọmọ Henadadi, ati àwọn Lefi pẹlu àwọn ọmọ wọn ati àwọn ìbátan wọn. +Wọ́n tún Bẹ̀rẹ̀ Ìjọ́sìn. +Nígbà ti àwọn ọ̀tá Juda ati ti Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn tí wó��n ti ìgbèkùn dé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli, +pẹlu àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí Osinapari, alágbára ati ọlọ́lá, kó wá láti máa gbé àwọn ìlú Samaria ati àwọn agbègbè tí wọ́n wà ní òdìkejì odò. +Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé náà nìyí: “Sí ọba Atasasesi, àwa iranṣẹ rẹ tí a wà ní agbègbè òdìkejì odò kí ọba. +A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé àwọn Juu tí wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wa ti lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí tún ìlú burúkú náà, tí ó kún fún ọ̀tẹ̀ kọ́. Wọ́n ti mọ odi rẹ̀, wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ parí ìpìlẹ̀ rẹ̀. +Kabiyesi, tí wọ́n bá fi lè kọ́ ìlú náà parí, tí wọ́n sì parí odi rẹ̀, wọn kò ní san owó ìṣákọ́lẹ̀ mọ́. Eléyìí yóo sì dín owó tí ń wọ àpò ọba kù. +A kò lè rí ohun tí kò dára kí á má sọ nítorí pé abẹ́ rẹ ni a ti ń jẹ; nítorí náà ni a fi gbọdọ̀ sọ fún ọba. +Ìmọ̀ràn wa ni pé, kí ọba pàṣẹ láti lọ wá àkọsílẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín ti kọ. Ẹ óo rí i pé ìlú ọlọ̀tẹ̀ ni ìlú yìí. Láti ìgbà laelae ni wọ́n ti jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba agbègbè wọn. Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi pa ìlú náà run. +A fẹ́ tẹ̀ ẹ́ mọ́ ọba létí pé bí àwọn eniyan wọnyi bá kọ́ ìlú yìí tí wọ́n sì mọ odi rẹ̀, kò ní ku ilẹ̀ kankan mọ́ fún ọba ní agbègbè òdìkejì odò.” +Ọba désì ìwé náà pada sí Rehumu, olórí ogun ati Ṣimiṣai, akọ̀wé, ati sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tí wọn ń gbé Samaria ati agbègbè òdìkejì odò yòókù. Ó ní, “Mo ki yín. +Wọ́n ka ìwé tí ẹ kọ sí wa, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi. +Mo pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìwádìí, a sì rí i pé láti ayébáyé ni ìlú yìí tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba wọn. +wọ́n wá sọ́dọ̀ Serubabeli, ati sọ́dọ̀ àwọn baálé baálé, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á jọ kọ́ ọ nítorí ọ̀kan náà ni wá, Ọlọrun yín ni àwa náà ń sìn, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà ayé Esaradoni, ọba Asiria, tí ó mú wa wá síhìn-ín.” +Àwọn ọba alágbára ti jẹ ní Jerusalẹmu, wọ́n ti jọba lórí gbogbo agbègbè òdìkejì odò, wọ́n sì gba owó ìṣákọ́lẹ̀, owó bodè lọ́wọ́ àwọn eniyan. +Nítorí náà, ẹ pàṣẹ pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró títí wọn yóo fi gbọ́ àṣẹ mìíràn láti ọ̀dọ̀ mi. +Ẹ má ṣe fi iṣẹ́ náà jáfara, nítorí tí ẹ bá fi falẹ̀, ó lè pa ọba lára.” +Lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n ka ìwé ọba tán sí etígbọ̀ọ́ Rehumu ati Ṣimiṣai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, Rehumu ati Ṣimiṣai yára lọ sí Jerusalẹmu pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọn sì fi ipá dá iṣẹ́ náà dúró. +Báyìí ni iṣẹ́ kíkọ́ ilé Ọlọrun ṣe dúró ní Jerusalẹmu títí di ọdún keji ìjọba Dariusi, ọba Pasia. +Ṣugbọn Serubabeli, Jeṣua, ati àwọn baálé baálé tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli dá wọn lóhùn pé, “A kò fẹ́ kí ẹ bá wa lọ́wọ́ sí kíkọ́ ilé OLUWA Ọlọrun wa. Àwa nìkan ni a óo kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí Kirusi, ọba Pasia, ti pa á láṣẹ fún wa.” +Nígbà náà ni àwọn tí wọ́n ti ń gbé ilẹ̀ náà mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá àwọn ará ilẹ̀ Juda, wọ́n sì dẹ́rùbà wọ́n, kí wọ́n má baà lè kọ́ tẹmpili náà. +Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn èké tí wọ́n ń san owó fún láti da ìpinnu àwọn ará Juda rú ní gbogbo àkókò ìjọba Kirusi, ọba Pasia, títí di àkókò Dariusi, ọba Pasia. +Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi, àwọn kan kọ ìwé wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn tí ń gbé Juda ati Jerusalẹmu. +Ní àkókò ìjọba Atasasesi, ọba Pasia, ni àwọn wọnyi dìde: Biṣilamu, Mitiredati, Tabeeli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù. Wọ́n kọ̀wé sí ọba Pasia ní èdè Aremia, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀. +Rehumu, olórí ogun, ati Ṣimiṣai, akọ̀wé, ni wọ́n kọ ìwé ẹ̀sùn sí ọba Atasasesi, nípa Jerusalẹmu ní orúkọ +àwọn mejeeji ati ti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n ṣẹ́kù pẹlu àwọn adájọ́, àwọn gomina ati àwọn ará Pasia, àwọn eniyan Ereki, àwọn ará Babiloni ati àwọn eniyan Susa, àwọn ará Elamu, +Àtakò Sí Títún Ilé Ọlọrun Kọ́. +Wolii Hagai ati wolii Sakaraya, ọmọ Ido, bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn Juu tí wọ́n wà ni Juda ati Jerusalẹmu ní orúkọ Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ó jẹ́ orí fún wọn. +A bèèrè orúkọ wọn, kí á baà lè kọ orúkọ olórí wọn sílẹ̀ láti fi ranṣẹ sí kabiyesi. +“Ìdáhùn tí wọ́n fún wa ni pé: ‘Iranṣẹ Ọlọrun ọ̀run ati ayé ni wá. Tẹmpili tí à ń tún kọ́ yìí, ọba olókìkí kan ni ó kọ́ ọ parí ní ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn. +Ṣugb���n nítorí pé àwọn baba wa mú Ọlọrun ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadinesari ọba Babiloni, ní ilẹ̀ Kalidea lọ́wọ́, òun ni ó wó tẹmpili yìí palẹ̀, tí ó sì kó àwọn eniyan ibẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Babilonia. +Ṣugbọn ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Babiloni, ó fi àṣẹ sí i pé kí wọ́n lọ tún tẹmpili náà kọ́. +Ó dá àwọn ohun èlò wúrà ati ti fadaka pada, tí Nebukadinesari kó ninu ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, lọ sí ilé oriṣa rẹ̀ ní Babiloni tẹ́lẹ̀. Gbogbo nǹkan wọnyi ni Kirusi ọba kó jáde kúrò ninu tẹmpili ní Babiloni, ó kó wọn lé Ṣeṣibasari lọ́wọ́, ẹni tí ó yàn ní gomina lórí Juda. +Ó sọ fún un nígbà náà pé, “Gba àwọn ohun èèlò wọnyi, kó wọn lọ sinu tẹmpili tí ó wà ní Jerusalẹmu, kí ẹ sì tún tẹmpili náà kọ́ sí ojú ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀.” +Ṣeṣibasari bá wá, ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ní Jerusalẹmu. Láti ìgbà náà ni iṣẹ́ ti ń lọ níbẹ̀ títí di ìsinsìnyìí, kò sì tíì parí.’ +“Nítorí náà, kabiyesi, tí ó bá dára lójú rẹ, jẹ́ kí wọ́n lọ wo ìwé àkọsílẹ̀ ní Babiloni bí kìí bá ṣe nítòótọ́ ni Kirusi pàṣẹ pé kí wọ́n tún ilé Ọlọrun kọ́ ní Jerusalẹmu. Lẹ́yìn náà jẹ́ kí á mọ ohun tí o fẹ́ kí á ṣe nípa ọ̀rọ̀ yìí.” +Nígbà tí Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli ati Jeṣua, ọmọ Josadaki gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lórí àtikọ́ ilé Ọlọrun ní Jerusalẹmu, àwọn wolii Ọlọrun mejeeji sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. +Ní àkókò kan náà, Tatenai, gomina agbègbè òdìkejì odò ati Ṣetari Bosenai ati gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn wá sí ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n bi wọ́n léèrè pé: “Ta ló fun yín láṣẹ láti kọ́ tẹmpili yìí ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ? +Ati pé, kí ni orúkọ àwọn tí wọ́n ń kọ́ ilé yìí?” +Ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu àwọn olórí Juu, wọn kò sì lè dá wọn dúró títí tí wọn fi kọ̀wé sí Dariusi ọba, tí wọ́n sì rí èsì ìwé náà gbà. +Ohun tí Tatenai ati Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn kọ sinu ìwé sí Dariusi ọba nìyí: +“Sí Dariusi ọba, kí ọba ó pẹ́. +“A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé, a lọ sí agbègbè Juda, a sì dé ilé tí wọ́n kọ́ fún Ọlọrun tí ó tóbi. Òkúta ńláńlá ni wọ́n fi ń kọ́ ọ, wọ́n sì ń tẹ́ pákó sára ògiri rẹ̀. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ náà, ó sì ń tẹ̀síwájú. +“A bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà wọn pé, ta ló fun wọn láṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ. +Iṣẹ́ Kíkọ́ Tẹmpili Tún Bẹ̀rẹ̀. +Dariusi ọba pàṣẹ pé kí wọ́n wádìí fínnífínní ninu àwọn ìwé àkọsílẹ̀ tí ó wà ní ààfin, ní ilẹ̀ Babiloni. +Kí wọ́n baà lè rú ẹbọ tí yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí Ọlọrun ọ̀run, kí wọ́n sì lè máa gbadura ibukun fún èmi ati àwọn ọmọ mi. +Siwaju sí i, mo tún pàṣẹ pé, bí ẹnikẹ́ni bá rú òfin mi yìí, kí wọ́n yọ ọ̀kan ninu igi òrùlé rẹ̀; kí wọ́n gbẹ́ ẹ ṣóńṣó, kí wọ́n tì í bọ̀ ọ́ láti ìdí títí dé orí rẹ̀. Kí wọ́n sì sọ ilé rẹ̀ di ààtàn. +Kí Ọlọrun, tí ó yan Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ibi ìsìn rẹ̀, pa ẹni náà run, kì báà ṣe ọba tabi orílẹ̀-èdè kan ni ó bá tàpá sí òfin yìí, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti wó ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu. Èmi Dariusi ọba ni mo pa àṣẹ yìí, ẹ sì gbọdọ̀ mú un ṣẹ fínnífínní.” +Tatenai, gomina, Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí Dariusi ọba pa fún wọn lẹ́sẹẹsẹ. +Àwọn àgbààgbà Juu ń kọ́ ilé náà, wọ́n sì ń ṣe àṣeyọrí pẹlu ìdálọ́kànle tí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Hagai ati Sakaraya, ọmọ Ido ń fún wọn. Wọ́n parí kíkọ́ tẹmpili náà bí Ọlọrun Israẹli ti pa á láṣẹ fún wọn ati gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Kirusi, ati ti Dariusi ati ti Atasasesi, àwọn ọba Pasia. +Wọ́n parí kíkọ́ Tẹmpili náà ní ọjọ́ kẹta oṣù Adari, ní ọdún kẹfa ìjọba Dariusi. +Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi ati àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé bá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ tẹmpili náà. +Ọgọrun-un ọ̀dọ́ akọ mààlúù, igba (200) àgbò, ati irinwo (400) ọ̀dọ́ aguntan ni wọ́n fi rú ẹbọ ìyàsímímọ́ náà. Wọ́n sì fi ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà Israẹli mejeejila. +Wọ́n sì fi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ipò wọn ninu iṣẹ́ ìsìn inú Tẹmpili, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé Mose. +Ní ọjọ́ kẹrinla, oṣù kinni ọdún tí ó tẹ̀lé e, àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ṣe ayẹyẹ Àjọ Ìrékọjá. +Ṣugbọn ní ìlú Ekibatana, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Media, ni wọ́n ti rí ìwé àkọsílẹ̀ kan tí ó kà báyìí pé: +Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ya ara wọn sí mímọ́ lápapọ̀, fún ayẹyẹ náà. Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá fún àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú, wọ́n pa fún àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ wọn, ati fún àwọn tìkara wọn. +Gbogbo àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ati àwọn tí wọ́n kọ ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà sílẹ̀ láti sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí wọn ń bá wọn gbé ní ilẹ̀ náà, tí wọ́n sì wá síbi ayẹyẹ náà pẹlu wọn, ni wọ́n jọ jẹ àsè náà. +Ọjọ́ meje ni wọ́n fi fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ Àjọ Àìwúkàrà, nítorí pé Ọlọrun ti fún wọn ní ayọ̀ nítorí inú ọba Asiria tí ó yọ́ sí wọn, tí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún ilé Ọlọrun Israẹli kọ́. +“Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi ni ó pàṣẹ pé kí wọn tún ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́ fún ìrúbọ ati fún ọrẹ ẹbọ sísun. Gíga ilé Ọlọrun náà gbọdọ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, (mita 27), kí ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgọta igbọnwọ, (mita 27). +Kí ògiri jẹ́ ìlè igi kan lórí ìlè òkúta mẹta. Ninu ilé ìṣúra ààfin ọba ni kí wọ́n ti mú owó kí wọ́n fi san owó iṣẹ́ náà. +Gbogbo ohun èlò ìṣúra wúrà ati fadaka inú tẹmpili ní Jerusalẹmu, tí Nebukadinesari kó lọ sí Babiloni, ni kí wọ́n kó pada wá sí Jerusalẹmu, kí wọ́n sì fi wọ́n sí ààyè wọn ninu ilé Ọlọrun.” +Nígbà náà ni Dariusi ọba désì ìwé Tatenai pada, ó ní,“Sí Tatenai, gomina agbègbè òdìkejì odò, ati Ṣetari Bosenai ati àwọn gomina ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n wà ní agbègbè òdìkejì odò. +Ẹ fi wọ́n sílẹ̀, ẹ má dí wọn lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí gomina Juda ati àwọn àgbààgbà Juu tún ilé Ọlọrun náà kọ́ síbi tí ó wà tẹ́lẹ̀. +Ati pé, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe láti ran àwọn àgbààgbà Juu lọ́wọ́ láti kọ́ ilé Ọlọrun náà pé: Ninu àpò ìṣúra ọba ati lára owó bodè ni kí ẹ ti mú, kí ẹ fi san gbogbo owó àwọn òṣìṣẹ́ ní àsanpé, kí iṣẹ́ lè máa lọ láìsí ìdádúró. +Lojoojumọ, ni kí ẹ máa fún àwọn alufaa tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu ní iye akọ mààlúù, àgbò, aguntan pẹlu ìwọ̀n ọkà, iyọ̀, ọtí waini ati òróró olifi, tí wọn bá bèèrè fún ẹbọ sísun sí Ọlọrun ọ̀run. +Wọ́n Rí Àkọsílẹ̀ Àṣẹ tí Kirusi Ọba Pa. +Lẹ́yìn náà, ní àkókò ìjọba Atasasesi, ọba Pasia, ọkunrin kan wà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹsira, ọmọ Seraaya, ọmọ Asaraya, ọmọ Hilikaya, +Nítorí Ẹsira fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sí kíkọ́ òfin OLUWA, ati pípa á mọ́ ati kíkọ́ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. +Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé tí ọba Atasasesi fún Ẹsira nìyí, +“Láti ọ̀dọ̀ Atasasesi ọba, sí Ẹsira, alufaa, tí ó tún jẹ́ akọ̀wé òfin Ọlọrun ọ̀run. +“Mo pàṣẹ jákèjádò ìjọba mi pé bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi bá fẹ́ bá ọ pada lọ sí Jerusalẹmu, kí ó máa bá ọ lọ; +nítorí pé èmi ati àwọn olùdámọ̀ràn mi meje ni a rán ọ lọ láti ṣe ìwádìí fínnífínní lórí Juda ati Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọrun rẹ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ, +ati pé kí o kó ọrẹ wúrà ati fadaka lọ́wọ́, tí ọba ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ fi ṣe ọrẹ àtinúwá fún Ọlọrun Israẹli, tí ibùgbé rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu. +O níláti kó gbogbo wúrà ati fadaka tí o bá rí ní gbogbo agbègbè Babiloni, ati ọrẹ àtinúwá tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn alufaa bá fínnúfẹ́dọ̀ dá jọ fún Tẹmpili Ọlọrun wọn ní Jerusalẹmu. +“Ṣíṣọ́ ni kí o ṣọ́ owó yìí ná: fi ra akọ mààlúù, àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan ati èròjà ẹbọ ohun jíjẹ ati ohun mímu, kí o fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ Tẹmpili Ọlọrun rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu. +Fadaka ati wúrà tí ó bá ṣẹ́kù, ìwọ ati àwọn eniyan rẹ, ẹ lò ó bí ó ti yẹ lójú yín ati gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun yín. +Gbogbo ohun èlò tí wọ́n kó fún ọ fún lílò ninu Tẹmpili Ọlọrun ni kí o kó lọ sí Jerusalẹmu, níwájú Ọlọrun. +ọmọ Ṣalumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu, +Bí o bá fẹ́ ohunkohun sí i fún lílò ninu Tẹmpili Ọlọrun rẹ, gbà á ninu ilé ìṣúra ọba. +“Èmi Atasasesi ọba pàṣẹ fún àwọn olùtọ́jú ilé ìṣúra ní agbègbè òdìkejì odò láti pèsè gbogbo nǹkan tí Ẹsira, alufaa akọ̀wé òfin Ọlọrun ọ̀run, bá fẹ́ fún un. +Ó láṣẹ láti gbà tó ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n kori ọkà, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n bati ọtí waini, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n bati òróró, ati ìwọ̀n iyọ̀ tí ó bá fẹ́. +Kí ẹ rí i pé ẹ tọ́jú gbogbo nǹkan tí Ọlọrun ọ̀run bá pa láṣẹ fún lílò ninu Tẹmpili rẹ̀, kí ibinu rẹ̀ má baà wá sórí ibùjókòó ọba ati àwọn ọmọ rẹ̀. +A tún fi ń ye yín pé kò bá òfin mu láti gba owó ìṣákọ́lẹ̀, tabi owó bodè, tabi owó orí lọ́wọ́ àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi, tabi àwọn akọrin, tabi àwọn aṣọ́nà, tabi àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tabi àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn ninu ilé Ọlọrun. +“Kí ìwọ Ẹsira, lo ọgbọ́n tí Ọlọrun rẹ fún ọ, kí o yan àwọn alákòóso ati àwọn adájọ́ tí wọ́n mọ òfin Ọlọrun rẹ, kí wọ́n lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè òdìkejì odò. Kí o sì kọ́ àwọn tí kò mọ òfin Ọlọrun rẹ kí àwọn náà lè mọ̀ ọ́n. +Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹríba fún òfin Ọlọrun rẹ ati àṣẹ ọba, pípa ni a óo pa á, tabi kí á wà á lọ kúrò ní ìlú, tabi kí á gba dúkìá rẹ̀, tabi kí á gbé e sọ sẹ́wọ̀n.” +Ẹsira bá dáhùn pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wa, tí ó fi sí ọba lọ́kàn láti ṣe ọ̀ṣọ́ sí tẹmpili Ọlọrun ní Jerusalẹmu, +tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí níwájú ọba, pẹlu àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pataki pataki. Nítorí pé OLUWA Ọlọrun wà pẹlu mi, mo ṣe ọkàn gírí, mo kó àwọn aṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli jọ, mo ní kí wọ́n bá mi kálọ.” +ọmọ Amaraya, ọmọ Asaraya, ọmọ Meraiotu, +ọmọ Serahaya, ọmọ Usi, ọmọ Buki, +ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, olórí alufaa. +Láti Babiloni ni Ẹsira tí à ń wí yìí ti dé. Akọ̀wé ni, ó sì já fáfá ninu òfin Mose, tí OLUWA Ọlọrun Israẹli fún wọn. Ọba fún un ní gbogbo nǹkan tí ó bèèrè, nítorí pé ó rí ojurere OLUWA Ọlọrun rẹ̀. +Ní ọdún keje ìjọba Atasasesi, díẹ̀ ninu àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti ìgbèkùn dé: àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn iranṣẹ ninu Tẹmpili, +wá sí Jerusalẹmu. Ní oṣù karun-un ọdún keje ìjọba Atasasesi ni Ẹsira dé sí Jerusalẹmu. +Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Babiloni ní ọjọ́ kinni oṣù kinni, ó sì dé Jerusalẹmu ní ọjọ́ kinni oṣù karun-un nítorí pé ó rí ojurere Ọlọrun. +Ẹsira Dé sí Jerusalẹmu. +Àkọsílẹ̀ àwọn eniyan ati àwọn baálé baálé tí wọ́n bá mi pada wá láti Babiloni ní àkókò Atasasesi, ọba, nìyí: +Ninu àwọn ọmọ Bani, Ṣelomiti, ọmọ Josifaya, ni olórí;orúkọ ọgọjọ (160) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. +Ninu àwọn ọmọ Bebai, Sakaraya, ọmọ Bebai, ni olórí;orúkọ eniyan mejidinlọgbọn ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. +Ninu àwọn ọmọ Asigadi, Johanani, ọmọ Hakatani, ni olórí;orúkọ aadọfa (110) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. +Ninu àwọn ọmọ Adonikamu,orúkọ àwọn tí wọ́n dé lẹ́yìn àwọn tí wọ́n kọ́ dé ni:Elifeleti, Jeueli ati Ṣemaaya; orúkọ ọgọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn. +Ninu àwọn ọmọ Bigifai, Utai ati Sakuri ni olórí,orúkọ aadọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn. +Mo pe gbogbo wọn jọ síbi odò tí ń ṣàn lọ sí Ahafa, a sì pàgọ́ sibẹ fún ọjọ́ mẹta. Nígbà tí mo wo ààrin àwọn eniyan ati àwọn alufaa, n kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀. +Mo bá ranṣẹ pe àwọn olórí wọn wọnyi: Elieseri, Arieli ati Ṣemaaya, Elinatani, Jaribu, Elinatani Natani, Sakaraya, ati Meṣulamu. Mo sì tún ranṣẹ pe Joiaribu ati Elinatani, tí wọ́n jẹ́ amòye. +Mo rán wọn lọ sọ́dọ̀ Ido, olórí àwọn eniyan ní Kasifia; mo ní kí wọ́n sọ fún Ido ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili pé kí wọ́n fi àwọn eniyan tí yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu ilé Ọlọrun wa ranṣẹ. +Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun, wọ́n fi Ṣerebaya, ọlọ́gbọ́n eniyan kan ranṣẹ sí wa. Ọmọ Israẹli ni, láti inú àwọn ọmọ Mahili, ninu ẹ̀yà Lefi: wọ́n fi ranṣẹ pẹlu àwọn ọmọ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogun. +Wọ́n tún rán Haṣabaya, òun ati Jeṣaya ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Merari; pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ wọn. Gbogbo wọn jẹ́ ogún, +Ninu àwọn ọmọ Finehasi, Geriṣomu ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Itamari, Daniẹli ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Dafidi, +láì tíì ka igba ó lé ogún (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tí Dafidi ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ láti máa ran àwọn ọmọ Lefi lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a kọ orúkọ wọn sinu ìwé. +Lẹ́yìn náà, mo pàṣẹ létí odò Ahafa pé kí á gbààwẹ̀, kí á lè rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọrun wa, kí á sì bèèrè ìtọ́sọ́nà fún ara wa ati àwọn ọmọ wa, ati gbogbo ohun ìní wa. +Ìtìjú ni ó jẹ́ fún mi láti bèèrè fún ọ̀wọ́ ọmọ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tí yóo dáàbò bò wá ninu ìrìn àjò wa, nítorí mo ti sọ fún ọba pé Ọlọrun wa a máa ṣe rere fún àwọn tí wọ́n bá ń gbọ́ tirẹ̀; Ṣugbọn a máa fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn kò bá tẹ̀lé e. +Nítorí náà, a gba ààwẹ̀, a sì gbadura sí Ọlọ́run, ó sì gbọ́ tiwa. +Lẹ́yìn náà mo ya àwọn àgbààgbà alufaa mejila sọ́tọ̀: Ṣerebaya, Haṣabaya ati mẹ́wàá ninu àwọn arakunrin wọn. +Mo wọn fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò tí ọba, ati àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ mú wá, ati èyí tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà níbẹ̀ náà mú wá fún ìlò ilé Ọlọrun. +Mo wọn ẹgbẹta lé aadọta (650) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ohun èlò fadaka tí a wọ̀n tó ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti wúrà, +ogún àwo wúrà tí wọ́n tó ẹgbẹrun (1000) ìwọ̀n diramu ati ohun èlò idẹ meji tí ó ń dán, tí ó sì níye lórí bíi wúrà. +Mo sọ fún wọn pé, “A yà yín ati gbogbo nǹkan wọnyi sí mímọ́ fún OLUWA. Fadaka ati wúrà jẹ́ ọrẹ àtinúwá fún OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín. +Ẹ máa tọ́jú wọn kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́ títí tí ẹ óo fi wọ̀n wọ́n níwájú àwọn olórí alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn baálé baálé Israẹli ní Jerusalẹmu ninu yàrá ilé OLUWA.” +Hatuṣi, ọmọ Ṣekanaya, ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Paroṣi, Sakaraya ni olórí;orúkọ aadọjọ (150) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. +Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi gba fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò náà, wọ́n kó wọn wá sinu ilé Ọlọrun wa ní Jerusalẹmu. +Ní ọjọ́ kejila oṣù kinni ni a kúrò ní odò Ahafa à ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. Ọlọrun wà pẹlu wa, ó dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ati àwọn dánàdánà. +Nígbà tí a dé Jerusalẹmu a wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. +Ní ọjọ́ kẹrin, a gbéra, a lọ sí ilé Ọlọrun, a wọn fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò, a sì kó wọn lé Meremoti, alufaa, ọmọ Uraya lọ́wọ́. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ níbẹ̀ ni Eleasari, ọmọ Finehasi, pẹlu àwọn ọmọ Lefi, Josabadi, ọmọ Jeṣua, ati Noadaya, ọmọ Binui. +A ka gbogbo wọn, a sì ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́. +Àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé fi akọ mààlúù mejila rú ọrẹ ẹbọ sísun sí Ọlọrun Israẹli fún ẹ̀yà Israẹli mejila, pẹlu àgbò mẹrindinlọgọrun-un, ọ̀dọ́ aguntan mẹtadinlọgọrun-un, ati òbúkọ mejila fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn ẹran wọnyi jẹ́ ẹbọ sísun fún Ọlọrun. +Wọ́n fún àwọn aláṣẹ ati àwọn gomina tí ọba yàn fún àwọn ìgbèríko tí wọ́n wà ní òdìkejì odò ní ìwé àṣẹ tí ọba pa; àwọn aláṣẹ náà sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn ati fún iṣẹ́ ilé Ọlọrun. +Ninu àwọn ọmọ Pahati Moabu, Eliehoenai, ọmọ Serahaya, ni olórí;orúkọ igba (200) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. +Ninu àwọn ọmọ Satu, Ṣekanaya, ọmọ Jahasieli, ni olórí;orúkọ ọọdunrun (300) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. +Ninu àwọn ọmọ Adini, Ebedi, ọmọ Jonatani, ni olórí;orúkọ aadọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. +Ninu àwọn ọmọ Elamu, Jeṣaya, ọmọ Atalaya, ni olórí;orúkọ aadọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. +Ninu àwọn ọmọ Ṣefataya, Sebadaya, ọmọ Mikaeli, ni olórí;orúkọ ọgọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. +Ninu àwọn ọmọ Joabu, Ọbadaya, ọmọ Jehieli, ni olórí;orúkọ igba eniyan ó lé mejidinlogun (218) ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀. +Àwọn tí Wọ́n Pada láti Oko Ẹrú. +Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n ní: “Àwọn ọmọ Israẹli pẹlu àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi kò ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò ninu ìwà ìríra àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Perisi ati àwọn ará Jebusi, ti àwọn ará Amoni ati àwọn ará Moabu, àwọn ará Ijipti, ati àwọn ará Amori. +“Áà, Ọlọrun wa, kí ni a tún lè wí lẹ́yìn èyí? Nítorí a ti kọ òfin rẹ sílẹ̀, +àní, òfin tí o ṣe, tí o fi rán àwọn wolii sí wa pé, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà yìí jẹ́ ilẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀gbin ati ohun ìríra, pẹlu ìwà ẹ̀gbin àwọn eniyan jákèjádò ilẹ̀ náà ti sọ ọ́ di aláìmọ́. +Nítorí náà, ẹ má fi àwọn ọmọbinrin yín fún àwọn ọmọkunrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbinrin wọn fún àwọn ọmọkunrin yín. Ẹ kò gbọdọ̀ wá ire wọn tabi alaafia, kí ẹ lè lágbára, kí ẹ lè jẹ èrè ilẹ̀ náà, kí ó sì lè jẹ́ ohun ìní fún àwọn ìran yín títí lae. +Lẹ́yìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa, nítorí ìwà burúkú wa ati ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí a dá, a rí i pé ìyà tí ìwọ Ọlọrun fi jẹ wá kéré sí ẹ̀ṣẹ̀ wa; o jẹ́ kí àwa tí a pọ̀ tó báyìí ṣẹ́kù sílẹ̀. +Ǹjẹ́ àwa tí a ṣẹ́kù yìí tún gbọdọ̀ máa rú òfin rẹ, kí á máa fẹ́ aya láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń ṣe ohun ìríra? Ǹjẹ́ o kò ní bínú sí wa tóbẹ́ẹ̀ tí o óo fi pa wá run, tí a kò fi ní ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan mọ́ tabi kí ẹyọ ẹnìkan sá àsálà? +OLUWA Ọlọrun Israẹli, olódodo ni ọ́, nítorí díẹ̀ ninu wa ṣẹ́kù tí a sá àsálà títí di òní yìí. A wà níwájú rẹ báyìí pẹlu ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó lè dúró níwájú rẹ báyìí.” +Wọ́n ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn fún ara wọn ati fún àwọn ọmọ wọn; àwọn ẹ̀yà mímọ́ sì ti darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká. Àwọn tí wọ́n jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà jù ni àwọn olórí ati àwọn eniyan pataki ní Israẹli.” +Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo fa aṣọ ati agbádá mi ya, láti fi ìbànújẹ́ mi hàn, mo sì fa irun orí ati irùngbọ̀n mi tu; mo sì jókòó pẹlu ìbànújẹ́. +Mo jókòó bẹ́ẹ̀ títí di àkókò ẹbọ àṣáálẹ́. Gbogbo àwọn tí wọ́n bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ọlọrun rọ̀gbà yí mi ká nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé. +Ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́, mo dìde kúrò níbi tí mo ti ń gbààwẹ̀ pẹlu aṣọ ati agbádá mi tí ó ya, mo kúnlẹ̀, mo sì tẹ́wọ́ sí OLUWA Ọlọrun mi, mo gbadura pé: +“Ọlọrun mi, ojú tì mí tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè gbójú sókè níwájú rẹ. Ìwà burúkú wa pọ̀ pupọ níwájú rẹ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ní ìpele ìpele, sì ga títí kan ọ̀run. +Láti ayé àwọn baba wa títí di ìsinsìnyìí, ni àwa eniyan rẹ ti ń dẹ́ṣẹ̀ lọpọlọpọ. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwọn ọba ati àwọn alufaa wa ti bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọba ilẹ̀ àjèjì; wọ́n pa wá, wọ́n dè wá ní ìgbèkùn, wọ́n sì kó wa lẹ́rù. A wá di ẹni ẹ̀gàn títí di òní. +Ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀ ní àkókò yìí, OLUWA Ọlọrun wa, o ṣàánú wa, o dá díẹ̀ sí ninu wa, à ń gbé ní àìléwu ní ibi mímọ́ rẹ. O jẹ́ kí ara dẹ̀ wá díẹ̀ ní oko ẹrú, o sì ń mú inú wa dùn. +Ẹrú ni wá; sibẹ ìwọ Ọlọrun wa kò fi wá sílẹ̀ ninu oko ẹrú, ṣugbọn o fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa, lọ́dọ̀ àwọn ọba Pasia; o sọ wá jí láti kọ́ ilé Ọlọrun wa, láti tún àwọn àlàpà rẹ̀ mọ ati láti mọ odi yí Judia ati Jerusalẹmu ká. +Ẹsira gbọ́ pé Àwọn Ọmọ Israẹli ń fẹ́ Àwọn Ọmọbinrin tí wọn kì í ṣe Juu. +Èmi Paulu, kì í ṣe eniyan ni ó pè mí láti jẹ́ aposteli, n kò sì ti ọ̀dọ̀ eniyan gba ìpè, Jesu Kristi ati Ọlọrun Baba, tí ó jí Jesu dìde, ni ó pè mí. +Ṣé ojurere eniyan ni mò ń wá nisinsinyii, tabi ti Ọlọrun? Àbí ohun tí ó wu eniyan ni mo fẹ́ máa ṣe? Bí ó bá jẹ́ pé ohun tí ó wu eniyan ni mò ń ṣe sibẹ, èmi kì í ṣe iranṣẹ Kristi. +Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìyìn rere tí mò ń waasu kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ eniyan. +Kì í ṣe ọwọ́ eniyan ni mo ti gbà á, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan ni ó kọ́ mi. Jesu Kristi ni ó fihàn mí. +Nítorí ẹ ti gbúròó ìwà mi látijọ́ nígbà tí mo wà ninu ẹ̀sìn ti Juu, pé mò ń fìtínà ìjọ Ọlọrun ju bí ó ti yẹ lọ. Mo sa gbogbo ipá mi láti pa á run. +Ninu ẹ̀sìn Juu, mo ta ọpọlọpọ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ninu orílẹ̀-èdè mi yọ. Mo ní ìtara rékọjá ààlà ninu àṣà ìbílẹ̀ àwọn baba-ńlá mi. +Ṣugbọn nígbà tí ó wu Ọlọrun, tí ó ti yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi, ó fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ pè mí, +láti fi Ọmọ rẹ̀ hàn ninu mi, kí n lè máa waasu ìyìn rere rẹ̀ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí ó pè mí, n kò bá ẹnikẹ́ni gbèrò, +n kò gòkè lọ sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ aposteli ṣiwaju mi, ṣugbọn mo lọ sí ilẹ̀ Arabia, láti ibẹ̀ ni mo tún ti pada sí Damasku. +Lẹ́yìn ọdún mẹta ni mo tó gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rí Peteru, mo sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹẹdogun. +Kò tún sí ọ̀kan ninu àwọn aposteli yòókù tí mo rí àfi Jakọbu arakunrin Oluwa. +Èmi ati gbogbo arakunrin tí ó wà lọ́dọ̀ mi ni à ń kọ ìwé yìí sí àwọn ìjọ Galatia. +Mo fi Ọlọrun jẹ́rìí pé kò sí irọ́ ninu ohun tí mò ń kọ si yín yìí! +Lẹ́yìn náà mo lọ sí agbègbè Siria ati ti Silisia. +Àwọn ìjọ Kristi tí ó wà ní Judia kò mọ̀ mí sójú. +Ṣugbọn wọ́n ń gbọ́ pé, “Ẹni tí ó ti ń fìtínà wa tẹ́lẹ̀ rí ti ń waasu ìyìn rere igbagbọ tí ó fẹ́ parun nígbà kan rí.” +Wọ́n bá ń yin Ọlọrun lógo nítorí mi. +Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia Ọlọrun, Baba wa, wà pẹlu yín ati ti Oluwa Jesu Kristi, +ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ ayé wa burúkú yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun Baba wa, +ẹni tí ògo yẹ fún lae ati laelae. Amin. +Ẹnu yà mí pé ẹ ti kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín nípa oore-ọ̀fẹ́ Kristi, ẹ ti yára yipada sí ìyìn rere mìíràn. +Kò sí ìyìn rere mìíràn ju pé àwọn kan wà tí wọn ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n fẹ́ yí ìyìn rere Kristi pada. +Ṣugbọn bí àwa fúnra wa tabi angẹli láti ọ̀run bá waasu ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a ti waasu fun yín, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé. +Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, mo tún ń wí nisinsinyii pé bí ẹnikẹ́ni bá waasu ìyìn rere mìíràn fun yín, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ gbà, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé. +Ìkíni. +Lẹ́yìn ọdún mẹrinla ni mo tó tún gòkè lọ sí Jerusalẹmu pẹlu Banaba. Mo mú Titu lọ́wọ́ pẹlu. +Nǹkankan ni wọ́n sọ fún wa, pé kí á ranti àwọn talaka láàrin àwọn tí ó kọlà. Òun gan-an ni mo sì ti dàníyàn láti máa ṣe. +Ṣugbọn nígbà tí Peteru wà ní Antioku, mo takò ó lojukooju nítorí ó ṣe ohun ìbáwí. +Nítorí kí àwọn kan tó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu dé, Peteru ti ń bá àwọn onigbagbọ tí kì í ṣe Juu jẹun. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí fà sẹ́yìn, ó ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, nítorí ó ń bẹ̀rù àwọn tí wọ́n fẹ́ kí gbogbo onigbagbọ kọlà. +Àwọn Juu yòókù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àgàbàgebè pẹlu Peteru. Wọ́n tilẹ̀ mú Banaba pàápàá wọ ẹgbẹ́ àgàbàgebè wọn! +Nígbà tí mo rí i pé ohun tí wọn ń ṣe kò bá òtítọ́ ìyìn rere mu, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ tí ó jẹ́ Juu bá ti ń ṣe bí àwọn yòókù, tí o kò ṣe bí àṣà àwọn Juu, kí ló dé tí o fi fẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ara wọn bíi Juu?” +Àwa tí a bí ní Juu, tí a kì í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, +mọ̀ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa iṣẹ́ òfin, àfi nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi. Àwa pàápàá gba Kristi Jesu gbọ́, kí Ọlọrun lè dá wa láre nípa igbagbọ ninu rẹ̀, kì í ṣe nípa iṣẹ́ òfin. +Nígbà tí à ń wá ọ̀nà ìdáláre ninu Kristi, bí a bá rí i pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni àwa náà, ṣé Kristi wá di iranṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Rárá o! +Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn ohun tí mo ti wó lulẹ̀ ni mo tún ń kọ́, èmi náà di ẹlẹ́ṣẹ̀. +Nítorí nípa òfin, mo ti kú sinu òfin kí n lè wà láàyè lọ́dọ̀ Ọlọrun. A ti kàn mí mọ́ agbelebu pẹlu Kristi. +Ọlọrun ni ó fihàn mí lójúran ni mo fi lọ. Mo wá ṣe àlàyé níwájú àwọn aṣaaju nípa ìyìn rere tí mò ń waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu. Níkọ̀kọ̀ ni a sọ̀rọ̀ kí gbogbo iré-ìje tí mò ń sá ati èyí tí mo ti sá má baà jẹ́ lásán. +Mo wà láàyè, ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo wà láàyè; Kristi ni ó ń gbé inú mi. Ìgbé-ayé tí mò ń gbé ninu ara nisinsinyii, nípa igbagbọ ninu Ọmọ Ọlọrun tí ó fẹ́ràn mi ni. Ó fẹ́ràn mi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí mi. +Kì í ṣe pé mo pa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tì. Nítorí bí eniyan bá lè di olódodo nípa ṣíṣe iṣẹ́ òfin, a jẹ́ pé Kristi kàn kú lásán ni. +Kì í ṣe ọ̀ranyàn ni pé kí á kọ Titu tí ó wà pẹlu mi nílà nítorí pé ọmọ ẹ̀yà Giriki ni. +Àwọn tí ó gbé ọ̀rọ̀ nípa ìkọlà Titu jáde ni àwọn arakunrin èké tí wọ́n yọ́ wá wo òmìnira wa tí a ní ninu Kristi Jesu, kí wọ́n lè sọ wá di ẹrú òfin. +Ṣugbọn a kò fi ìgbà kankan gbà wọ́n láyè rárá, kí ó má dàbí ẹni pé ọ̀rọ̀ tiwọn ni ó borí, kí òtítọ́ ìyìn rere lè wà pẹlu yín. +Ṣugbọn àwọn tí wọn ń pè ní aṣaaju ninu wọn kò kọ́ mi ní ohun titun kan. Ohun tí ó mú kí n sọ̀rọ̀ báyìí ni pé kò sí ohun tí ó kàn mí ninu ọ̀rọ̀ a-jẹ́-aṣaaju tabi a-kò-jẹ́-aṣaaju. Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju. +Ṣugbọn wọ́n wòye pé a ti fi iṣẹ́ ajíyìnrere fún àwọn aláìkọlà fún mi ṣe, gẹ́gẹ́ bí a ti fún Peteru ní iṣẹ́ ajíyìnrere fún àwọn tí ó kọlà. +Nítorí ẹni tí ó fún Peteru ní agbára láti ṣiṣẹ́ láàrin àwọn tí wọ́n kọlà ni ó fún mi ní agbára láti ṣiṣẹ́ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. +Nígbà tí Jakọbu, Peteru ati Johanu, tí àwọn eniyan ń wò bí òpó ninu ìjọ, rí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun ti fi fún mi, wọ́n bọ èmi ati Banaba lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì ìdàpọ̀, wọ́n ní kí àwa lọ sáàrin àwọn tí kì í ṣe Juu bí àwọn náà ti ń lọ sáàrin àwọn tí ó kọlà. +Àwọn Aposteli yòókù Gba Paulu Bí Aposteli. +Ẹ̀yin ará Galatia, ẹ mà kúkú gọ̀ o! Ta ni ń dì yín rí? Ẹ̀yin tí a gbé Jesu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu sí níwájú gbangba! +A ti fi gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ òfin gégùn-ún. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí kò bá máa ṣe ohun gbogbo tí a kọ sinu ìwé òfin.” +Ó dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa òfin, nítorí a kà á pé, “Olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.” +Ṣugbọn òfin kì í ṣe igbagbọ, nítorí a kà á pé, “Ẹni tí ó bá ń pa gbogbo òfin mọ́ yóo wà láàyè nípa wọn.” +Kristi ti rà wá pada kúrò lábẹ́ ègún òfin, ó ti di ẹni ègún nítorí tiwa, nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí wọ́n bá gbé kọ́ sórí igi.” +Ìdí rẹ̀ ni pé kí ibukun Abrahamu lè kan àwọn tí kì í ṣe Juu nípasẹ̀ Kristi Jesu, kí á lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa igbagbọ. +Ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kí á lo àkàwé kan ninu ìrírí eniyan. Gẹ́gẹ́ bí àṣà, nígbà tí a bá ti ṣe majẹmu tán, kò sí ẹni tí ó lè yí i pada tabi tí ó lè fi gbolohun kan kún un. +Nígbà tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún Abrahamu ati irú-ọmọ rẹ̀, kì í ṣe ọ̀rọ̀ gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ ni Ọlọrun ń sọ, ṣugbọn ọmọ kanṣoṣo ni ó tọ́ka sí. Ó sọ pé, “Ati fún irú-ọmọ rẹ.” Ọmọ náà ni Kristi. +Kókó ohun tí mò ń sọ ni pé òfin tí ó dé lẹ́yìn ọgbọnlenirinwo (430) ọdún kò lè pa majẹmu tí Ọlọrun ti ṣe rẹ́. Ìlérí tí Ọlọrun ti ṣe kò lè torí rẹ̀ di òfo. +Nítorí bí eniyan bá lè di ajogún nípa òfin, a jẹ́ pé kì í tún ṣe ìlérí mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni nípa ìlérí ni Ọlọrun fún Abrahamu ní ogún. +Ipò wo wá ni òfin wà? Kí eniyan lè mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọrun ṣe fi òfin kún ìlérí, títí irú-ọmọ tí ó ṣe ìlérí rẹ̀ fún yóo fi dé. Láti ọwọ́ àwọn angẹli ni alárinà ti gba òfin. +Nǹkankan péré ni mo fẹ́ bi yín: ṣé nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ fi gba Ẹ̀mí ni tabi nípa ìgbọràn igbagbọ? +Ètò tí alárinà bá lọ́wọ́ sí ti kúrò ní ti ẹyọ ẹnìkan. Ṣugbọn ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọrun. +Ǹjẹ́ òfin wá lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọrun ni bí? Rárá o! Bí ó bá jẹ́ pé òfin tí a fi fúnni lè sọ eniyan di alààyè, eniyan ìbá lè di olódodo nípa òfin. +Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ ti sọ pé ohun gbogbo wà ninu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ kí á lè fi ìlérí nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi fún gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́. +Ṣugbọn kí àkókò igbagbọ yìí tó tó, a wà ninu àtìmọ́lé lábẹ́ òfin, a sé wa mọ́ títí di àkókò igbagbọ yìí. +Èyí ni pé òfin jẹ́ olùtọ́ wa títí Kristi fi dé, kí á lè dá wa láre nípa igbagbọ. +Nígbà tí àkókò igbagbọ ti dé, a kò tún nílò olùtọ́ mọ́. +Nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ Ọlọrun nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu. +Nítorí gbogbo ẹni tí ó ti ṣe ìrìbọmi nípa igbagbọ ninu Kristi ti gbé Kristi wọ̀. +Kò tún sí ọ̀rọ̀ pé ẹnìkan ni Juu, ẹnìkan ni Giriki mọ́, tabi pé ẹnìkan jẹ́ ẹrú tabi òmìnira, ọkunrin tabi obinrin. Nítorí gbogbo yín ti di ọ̀kan ninu Kristi Jesu. +Tí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, a jẹ́ pé ẹ jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, ẹ sì di ajogún ìlérí. +Àṣé ẹ ṣiwèrè tóbẹ́ẹ̀! Ẹ bẹ̀rẹ̀ pẹlu nǹkan ti ẹ̀mí, ẹ wá fẹ́ fi nǹkan ti ara parí! +Gbogbo ìyà tí ẹ ti jẹ á wá jẹ́ lásán? Kò lè jẹ́ lásán! +Ṣé nítorí pé ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ òfin ni ẹni tí ó fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fun yín ṣe fun yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí ó tún ṣiṣẹ́ ìyanu láàrin yín, tabi nítorí pé ẹ gbọ́ ìyìn rere, ẹ sì gbà á? +Bí Abrahamu ti gba Ọlọrun gbọ́, tí Ọlọrun wá gbà á gẹ́gẹ́ bí olódodo, +kí ó ye yín pé àwọn ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ni ọmọ Abrahamu. +Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun yóo fi dá àwọn tí kì í ṣe Juu láre, ó waasu ìyìn rere fún Abrahamu pé, “Gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo di ẹni ibukun nípasẹ̀ rẹ.” +Èyí ni pé àwọn tí ó gbàgbọ́ rí ibukun gbà, bí Abrahamu ti rí ibukun gbà nítorí pé ó gbàgbọ́. +Òfin tabi Igbagbọ. +Ohun tí mò ń sọ ni pé nígbà tí àrólé bá wà ní ọmọde kò sàn ju ẹrú lọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó ni gbogbo nǹkan tí Baba rẹ̀ fi sílẹ̀. +Ẹ̀ ń ya oríṣìíríṣìí ọjọ́ sọ́tọ̀, ẹ̀ ń ranti oṣù titun, àkókò ati àjọ̀dún! +Ẹ̀rù yín ń bà mí pé kí gbogbo làálàá mi lórí yín má wá jẹ́ lásán! +Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín ni, ẹ dàbí mo ti dà nítorí èmi náà ti dàbí yín. Ẹ kò ṣẹ̀ mí rárá. +Ẹ mọ̀ pé àìlera ni ó mú kí n waasu ìyìn rere fun yín ní àkọ́kọ́. +Ẹ kò kọ ohun tí ó jẹ́ ìdánwò fun yín ninu ara mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò fi mí ṣẹ̀sín, ṣugbọn ẹ gbà mí bí ẹni pé angẹli Ọlọrun ni mí, àní bí ẹni pé èmi ni Kristi Jesu. +Kò sí bí inú yín kò ti dùn tó nígbà náà. Kí ni ó wá dé nisinsinyii! Nítorí mo jẹ́rìí yín pé bí ó bá ṣeéṣe nígbà náà ẹ̀ bá yọ ojú yín fún mi! +Mo wá ti di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fun yín! +Kì í ṣe ire yín ni àwọn tí wọn ń ṣaájò yín ń wá. Ohun tí wọn ń wá ni kí wọ́n lè fi yín sinu àhámọ́, kí ẹ lè máa wá wọn. +Ó dára kí á máa wá ara ẹni ninu ohun rere nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí mo bá wà pẹlu yín nìkan. +Ẹ̀yin ọmọ mi, ara ń ni mí nítorí yín, bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́, títí ẹ óo fi di àwòrán Kristi. +Nítorí pé òun alára wà lábẹ́ àwọn olùtọ́jú, ohun ìní rẹ̀ sì wà ní ìkáwọ́ àwọn alámòójútó títí di àkókò tí baba rẹ̀ ti dá. +Ó wù mí bíi pé kí n wà lọ́dọ̀ yín nisinsinyii, kí n yí ohùn mi pada, nítorí ọ̀rọ̀ yín rú mi lójú. +Ẹ sọ fún mi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ wà lábẹ́ òfin: ṣé ẹ gbọ́ ohun tí òfin wí? +Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé Abrahamu ní ọmọ meji, ọ̀kan ọmọ ẹrubinrin, ọ̀kan ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira. +Ó bí ọmọ ti ẹrubinrin nípa ìfẹ́ ara, ṣugbọn ó bí ọmọ ti obinrin tí ó ní òmìnira nípa ìlérí Ọlọrun. +Àkàwé ni nǹkan wọnyi. Obinrin mejeeji yìí jẹ́ majẹmu meji, ọ̀kan láti òkè Sinai, tí ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹrú; èyí ni Hagari. +Hagari ni òkè Sinai ní Arabia tíí ṣe àpẹẹrẹ Jerusalẹmu ti òní. Ó wà ninu ipò ẹrú pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. +Ṣugbọn Jerusalẹmu ti òkè wà ninu òmìnira. Òun ni ìyá wa. +Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Máa yọ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ rí.Sọ̀rọ̀ kí o kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí.Nítorí àwọn ọmọ àgàn pọ̀ ju ti obinrin tí ó ní ọkọ lọ.” +Ṣugbọn ẹ̀yin, ará, ọmọ ìlérí bíi Isaaki ni yín. +Ṣugbọn bí ó ti rí látijọ́, tí ọmọ tí a bí nípa ìfẹ́ ara ń ṣe inúnibíni ọmọ tí a bí nípa Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà títí di ìsinsìnyìí. +Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu wa. Nígbà tí a jẹ́ ọmọde, a jẹ́ ẹrú àwọn oríṣìíríṣìí ẹ̀mí tí a kò fojú rí. +Ṣugbọn kí ni Ìwé Mímọ́ wí? Ó ní, “Lé ẹrubinrin ati ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrubinrin kò ní bá ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira pín ogún baba wọn.” +Nítorí náà, ará, a kì í ṣe ọmọ ẹrubinrin, ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira ni wá. +Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu, +kí ó lè ra àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin pada, kí á lè sọ wá di ọmọ. +Ọlọrun rán ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ sinu ọkàn wa, Ẹ̀mí yìí ń ké pé, “Baba!” láti fihàn pé ọmọ ni ẹ jẹ́. +Nítorí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́ bíkòṣe ọmọ. Bí ẹ bá wá jẹ́ ọmọ, ẹ di ajogún nípasẹ̀ iṣẹ́ Ọlọrun. +Ṣugbọn nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọrun, ẹ di ẹrú àwọn ẹ̀dá tí kì í ṣe Ọlọrun. +Nisinsinyii ẹ mọ Ọlọrun, tabi kí á kúkú wí pé Ọlọrun mọ̀ yín. Báwo ni ẹ ṣe tún fẹ́ yipada sí àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí wọ́n jẹ́ aláìlera ati aláìní, tí ẹ tún fẹ́ máa lọ ṣe ẹrú wọn? +Paulu Ní Àníyàn fún Àwọn Ará Galatia. +Irú òmìnira yìí ni a ní. Kristi ti sọ wá di òmìnira. Ẹ dúró ninu rẹ̀, kí ẹ má sì tún gbé àjàgà ẹrú kọ́rùn mọ́. +Mo ní ìdánilójú ninu Oluwa pé ẹ kò ní ní ọkàn mìíràn. Ṣugbọn ẹni tí ó ń yọ yín lẹ́nu yóo gba ìdájọ́ Ọlọrun, ẹni yòówù kí ó jẹ́. +Ará, tí ó bá jẹ́ pé iwaasu pé kí eniyan kọlà ni mò ń wà, kí ló dé tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ǹjẹ́ a ti mú ohun ìkọsẹ̀ agbelebu Kristi kúrò? +Ìbá wù mí kí àwọn tí ó ń yọ yín lẹ́nu kúkú gé ara wọn sọnù patapata! +Òmìnira ni a pè yín sí, ẹ̀yin ará, ṣugbọn kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín fún ìtẹ́lọ́rùn ara yín, ìfẹ́ ni kí ẹ máa fi ran ara yín lọ́wọ́. +Nítorí gbolohun kan kó gbogbo òfin já, èyí ni pé “Fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.” +Ṣugbọn bí ẹ bá ń bá ara yín jà, tí ẹ̀ ń bu ara yín ṣán, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa ara yín run. +Ṣugbọn mò ń sọ fun yín pé kí ẹ jẹ́ kí Ẹ̀mí máa darí ìgbé-ayé yín, tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ kò ní mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ṣẹ. +Nítorí ohun tí ara ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí; bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí Ẹ̀mí ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti ara. Ẹ̀mí ati ara lòdì sí ara wọn. Àyọrísí rẹ̀ ni pé ẹ kì í lè ṣe àwọn ohun tí ó wù yín láti ṣe. +Bí Ẹ̀mí bá ń darí yín, ẹ kò sí lábẹ́ òfin. +Àwọn iṣẹ́ ara farahàn gbangba. Àwọn ni àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà; +Èmi Paulu ni mo wí fun yín pé bí ẹ bá kọlà, Kristi kò ṣe yín ní anfaani kankan. +ìbọ̀rìṣà, oṣó, odì-yíyàn, ìjà, owú-jíjẹ, ìrúnú, ọ̀kánjúwà, ìyapa, rìkíṣí; +inú burúkú, ìmutípara, àríyá àwọn ọ̀mùtí ati irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ohun tí mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, ni mo tún ń sọ fun yín, pé àwọn tí ó ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ní jogún ìjọba Ọlọrun. +Ṣugbọn èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, alaafia, sùúrù, àánú, iṣẹ́ rere, ìṣòtítọ́, +ìwà pẹ̀lẹ́, ìsẹ́ra-ẹni. Kò sí òfin kan tí ó lòdì sí irú nǹkan báwọ̀nyí. +Àwọn tíí ṣe ti Kristi Jesu ti kan àwọn nǹkan ti ara mọ́ agbelebu pẹlu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ati ìgbádùn ara. +Bí a bá wà láàyè nípa Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí á máa gbé ìgbé-ayé ti Ẹ̀mí. +Ẹ má jẹ́ kí á máa ṣe ògo asán, kí á má máa rú ìjà sókè láàrin ara wa, kí á má sì máa jowú ara wa. +Mo tún wí pé gbogbo ẹni tí a bá kọ nílà di ajigbèsè; ó níláti pa gbogbo òfin mọ́. +Ẹ ti ya ara yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fẹ́ ìdáláre nípa òfin. Ẹ ti yapa kúrò ní ọ̀nà oore-ọ̀fẹ́. +Ṣugbọn ní tiwa, nípasẹ̀ Ẹ̀mí ni à ń retí ìdáláre nípa igbagbọ. +Nítorí ọ̀ràn pé a kọlà tabi a kò kọlà kò jẹ́ nǹkankan fún àwọn tí ó wà ninu Kristi Jesu. Ohun tí ó ṣe kókó ni igbagbọ tí ó ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́. +Ẹ ti ń sáré ìje dáradára bọ̀. Ta ni kò jẹ́ kí ẹ gba òtítọ́ mọ́? +Ìyípadà ọkàn yín kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó pè yín. +Ìwúkàrà díẹ̀ níí mú kí gbogbo ìyẹ̀fun wú sókè. +Òmìnira Onigbagbọ. +Ará, bí ẹ bá ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ẹnìkan lọ́wọ́, kí ẹ̀yin tí ẹ̀mí ń darí ìgbé-ayé yín mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò pẹlu ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ṣọ́ra rẹ, kí á má baà dán ìwọ náà wò. +Nítorí náà, bí a bá ti ń rí ààyè kí á máa ṣe oore fún gbogbo eniyan, pàápàá fún àwọn ìdílé onigbagbọ. +Ọwọ́ ara mi ni mo fi kọ ìwé yìí si yín, ẹ wò ó bí ó ti rí gàdàgbà-gadagba! +Gbogbo àwọn tí wọn ń fẹ́ kí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn mọ̀ wọ́n ní ẹni rere ni wọ́n fẹ́ fi ipá mu yín kọlà, kí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn má baà ṣe inúnibíni sí wọn nítorí agbelebu Kristi. +Nítorí àwọn tí wọ́n kọlà pàápàá kì í pa gbogbo òfin mọ́. Ṣugbọn wọ́n fẹ́ kí ẹ kọlà kí wọ́n máa fi yín fọ́nnu pé àwọn mu yín kọlà. +Ṣugbọn ní tèmi, kí á má rí i pé mò ń fọ́nnu kiri àfi nítorí agbelebu Oluwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ayé yìí ti di ohun tí a kàn mọ́ agbelebu lójú mi, tí èmi náà sì di ẹni tí a kàn mọ́ agbelebu lójú rẹ̀. +Nítorí ati a kọlà ni, ati a kò kọlà ni, kò sí èyí tí ó já mọ́ nǹkankan. Ohun tí ó ṣe pataki ni ẹ̀dá titun. +Kí alaafia ati àánú Ọlọrun kí ó wà pẹlu gbogbo àwọn tí ó bá ń gbé ìgbé-ayé wọn nípa ìlànà yìí, ati pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun. +Láti ìgbà yìí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu mọ́, nítorí ojú pàṣán wà ní ara mi tí ó fihàn pé ti Jesu ni mí. +Ará, kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Oluwa wa kí ó wà pẹlu yín. Amin. +Ẹ máa ran ara yín lẹ́rù, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú òfin Kristi ṣẹ. +Nítorí bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ pataki nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ara rẹ̀ ni ó ń tàn jẹ. +Kí olukuluku yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà yóo lè ṣògo lórí iṣẹ́ tirẹ̀, kì í ṣe pé kí ó máa fi iṣẹ́ tirẹ̀ wé ti ẹlòmíràn. +Nítorí olukuluku gbọdọ̀ ru ẹrù tirẹ̀. +Ẹni tí ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ ìyìn rere gbọdọ̀ máa pín olùkọ́ rẹ̀ ninu àwọn nǹkan rere rẹ̀. +Ẹ má tan ara yín jẹ: eniyan kò lè mú Ọlọrun lọ́bọ. Ohunkohun tí eniyan bá gbìn ni yóo ká. +Nítorí àwọn tí ó bá ń gbin nǹkan ti Ẹ̀mí yóo ká àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí, tíí ṣe ìyè ainipẹkun. +Kí á má ṣe jẹ́ kí ó sú wa láti ṣe rere, nítorí nígbà tí ó bá yá, a óo kórè rẹ̀, bí a kò bá jẹ́ kí ó rẹ̀ wá. +Ẹ Máa Ran Ara Yín Lọ́wọ́. +Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, +Ó sọ ìyàngbẹ ilẹ̀ náà ní ilẹ̀, ó sì sọ omi tí ó wọ́jọ pọ̀ ní òkun. Ó wò ó, ó sì rí i pé ó dára. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ hu koríko jáde oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu, ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Ilẹ̀ bá hu koríko jáde, oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ó ní irúgbìn ninu. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. +Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹta. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí àwọn ìmọ́lẹ̀ wà ní ojú ọ̀run, láti fi ààlà sí ààrin ọ̀sán ati òru, kí wọ́n wà láti jẹ́ àmì, ati láti máa fi àkókò àjọ̀dún, ọjọ́, ati ọdún hàn, +kí wọ́n sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti máa tàn sórí ilẹ̀ ayé, ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Ọlọrun dá ìmọ́lẹ̀ ńlá meji: ó dá oòrùn láti máa jọba ọ̀sán, ati òṣùpá láti máa jọba òru, ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹlu. +Ọlọrun fi wọ́n sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé, +láti máa jọba lórí ọ̀sán ati òru, ati láti fi ààlà sí ààrin ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. +Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹrin. +ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi kún fún oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè, kí ojú ọ̀run sì kún fún àwọn ẹyẹ. +Ó dá àwọn ẹranko ńláńlá inú omi ati oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. +Ọlọrun súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i lórí ilẹ̀.” +Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ karun-un. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mú oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè jáde: oríṣìíríṣìí ẹran ọ̀sìn, oríṣìíríṣìí ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀ ati oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́, ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá gbogbo wọn, ó wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. +Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á dá eniyan ní àwòrán ara wa, kí ó rí bíi wa, kí wọ́n ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko ati lórí gbogbo ayé ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà lórí ilẹ̀.” +Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá eniyan ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn. +Ó súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo ayé. Kí ayé wà ní ìkáwọ́ yín, kí ẹ ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú omi, lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, ati lórí gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé.” +Ọlọrun tún wí pé, “Mo ti pèsè gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso ati igi tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu fún yín láti jẹ. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà. +Bẹ́ẹ̀ ni mo sì ti pèsè àwọn ewéko fún oúnjẹ àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Ọlọrun wo gbogbo ohun tí ó dá, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹfa. +Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn. +Ó sọ ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, ó sì sọ òkùnkùn ní òru. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kinni. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí awọsanma wà láàrin omi, kí ó pín omi sí ọ̀nà meji, kí ó sì jẹ́ ààlà láàrin omi tí ó wà lókè awọsanma náà ati èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. +Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Ọlọrun sọ awọsanma náà ní ojú ọ̀run. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ keji. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́jọ pọ̀ sí ojú kan, kí ìyàngbẹ ilẹ̀ lè farahàn, ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Ìtàn Bí A ṣe Dá Ayé. +Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, +Ó sọ ìyàngbẹ ilẹ̀ náà ní ilẹ̀, ó sì sọ omi tí ó wọ́jọ pọ̀ ní òkun. Ó wò ó, ó sì rí i pé ó dára. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ hu koríko jáde oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu, ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Ilẹ̀ bá hu koríko jáde, oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ó ní irúgbìn ninu. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. +Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹta. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí àwọn ìmọ́lẹ̀ wà ní ojú ọ̀run, láti fi ààlà sí ààrin ọ̀sán ati òru, kí wọ́n wà láti jẹ́ àmì, ati láti máa fi àkókò àjọ̀dún, ọjọ́, ati ọdún hàn, +kí wọ́n sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti máa tàn sórí ilẹ̀ ayé, ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Ọlọrun dá ìmọ́lẹ̀ ńlá meji: ó dá oòrùn láti máa jọba ọ̀sán, ati òṣùpá láti máa jọba òru, ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹlu. +Ọlọrun fi wọ́n sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé, +láti máa jọba lórí ọ̀sán ati òru, ati láti fi ààlà sí ààrin ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. +Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹrin. +ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi kún fún oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè, kí ojú ọ̀run sì kún fún àwọn ẹyẹ. +Ó dá àwọn ẹranko ńláńlá inú omi ati oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. +Ọlọrun súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i lórí ilẹ̀.” +Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ karun-un. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mú oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè jáde: oríṣìíríṣìí ẹran ọ̀sìn, oríṣìíríṣìí ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀ ati oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́, ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá gbogbo wọn, ó wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. +Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á dá eniyan ní àwòrán ara wa, kí ó rí bíi wa, kí wọ́n ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko ati lórí gbogbo ayé ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà lórí ilẹ̀.” +Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá eniyan ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn. +Ó súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo ayé. Kí ayé wà ní ìkáwọ́ yín, kí ẹ ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú omi, lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, ati lórí gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé.” +Ọlọrun tún wí pé, “Mo ti pèsè gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso ati igi tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu fún yín láti jẹ. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà. +Bẹ́ẹ̀ ni mo sì ti pèsè àwọn ewéko fún oúnjẹ àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Ọlọrun wo gbogbo ohun tí ó dá, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹfa. +Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn. +Ó sọ ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, ó sì sọ òkùnkùn ní òru. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kinni. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí awọsanma wà láàrin omi, kí ó pín omi sí ọ̀nà meji, kí ó sì jẹ́ ààlà láàrin omi tí ó wà lókè awọsanma náà ati èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. +Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Ọlọrun sọ awọsanma náà ní ojú ọ̀run. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ keji. +Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́jọ pọ̀ sí ojú kan, kí ìyàngbẹ ilẹ̀ lè farahàn, ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Ìtàn Bí A ṣe Dá Ayé. +Ìran Noa nìyí: àwọn ọmọ rẹ̀ ni Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Lẹ́yìn ìkún omi, àwọn mẹtẹẹta bí ọmọ tiwọn. +Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Babeli, Ereki ati Akadi. Àwọn ìlú mẹtẹẹta yìí wà ní ilẹ̀ Babiloni. +Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Asiria, ó sì tẹ Ninefe dó, ati Rehoboti Iri, ati Kala, +ati ìlú ńlá tí wọn ń pè ní Reseni tí ó wà láàrin Ninefe ati Kala. +Ijipti ni ó bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Nafutuhimu, +Patirusimu, Kasiluhimu, (lọ́dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistia ti ṣẹ̀) ati Kafitorimu. +Àkọ́bí Kenaani ni Sidoni, òun náà ni ó bí Heti. +Kenaani yìí kan náà ni baba ńlá àwọn ará Jebusi, àwọn ará Amori, àwọn ará Girigaṣi, +àwọn ará Hifi, àwọn ará Ariki, àwọn ará Sini, +àwọn ará Arifadi, àwọn ará Semari, ati àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn náà ni ìran àwọn ará Kenaani tàn káàkiri. +Ilẹ̀ àwọn ará Kenaani bẹ̀rẹ̀ láti Sidoni, ní ìhà Gerari, ó lọ títí dé Gasa, ati sí ìhà Sodomu, Gomora, Adima, ati Seboimu títí dé Laṣa. +Àwọn ọmọ Jafẹti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki ati Tirasi. +Àwọn ọmọ Hamu nìwọ̀nyí ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀, oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè. +Ṣemu, ẹ̀gbọ́n Jafẹti, náà bí àwọn ọmọ tirẹ̀, òun ni baba ńlá gbogbo àwọn ọmọ Eberi. +Òun náà ni ó bí Elamu, Aṣuri, Apakiṣadi, Ludi, ati Aramu. +Àwọn ọmọ Aramu ni: Usi, Huli, Geteri, ati Maṣi. +Apakiṣadi ni baba Ṣela, Ṣela sì ni baba Eberi. +Àwọn ọmọkunrin meji ni Eberi bí, orúkọ ekinni ni Pelegi, nítorí pé ní ìgbà tirẹ̀ ni ayé pínyà, orúkọ ekeji ni Jokitani. +Jokitani ni baba Alimodadi, Ṣelefu, Hasamafeti, Jera, +Hadoramu, Usali, Dikila, +Obali, Abimaeli, +Ṣeba, Ofiri, Hafila, ati Jobabu, àwọn ni ọmọ Jokitani. +Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣikenasi, Rifati, ati Togama. +Ilẹ̀ tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Meṣa, ní ìhà Sefari títí dé ilẹ̀ olókè ti ìhà ìlà oòrùn. +Àwọn ni ọmọ Ṣemu, ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀. Oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè. +Ìdílé àwọn ọmọ Noa ni wọ́n jẹ́, gẹ́gẹ́ bí ìran wọn ní orílẹ̀-èdè wọn. Lára wọn ni àwọn orílẹ̀-èdè ti tàn ká gbogbo ayé lẹ́yìn ìkún omi. +Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣai, Taṣiṣi, Kitimu ati Dodanimu. +Àwọn ni baba ńlá àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ati àwọn erékùṣù, tí wọ́n tàn káàkiri. Àwọn ọmọ Jafẹti nìwọ̀nyí ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀. Oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè. +Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ijipti, Puti ati Kenaani. +Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabita, Raama ati Sabiteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba ati Dedani. +Kuṣi ni baba Nimrodu, Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí wọ́n mọ̀ ní akọni láyé. +Pẹlu àtìlẹ́yìn OLUWA, Nimrodu di ògbójú ọdẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n máa ń fi orúkọ rẹ̀ súre fún eniyan pé, “Kí OLUWA sọ ọ́ di ògbójú ọdẹ bíi Nimrodu.” +Ìran Àwọn Ọmọ Noa. +Nígbà kan èdè kan ṣoṣo ni ó wà láyé, ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan ni gbogbo wọ́n sì ń lò. +Àkọsílẹ̀ ìran Ṣemu nìyí: ọdún keji lẹ́yìn tí ìkún omi ṣẹlẹ̀, tí Ṣemu di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ni ó bí Apakiṣadi. +Lẹ́yìn tí Ṣemu bí Apakiṣadi tán, ó tún gbé ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Nígbà tí Apakiṣadi di ẹni ọdún marundinlogoji ni ó bí Ṣela. +Ó tún gbé ọdún mẹtalenirinwo (403) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Nígbà tí Ṣela di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi. +Ó tún gbé ọdún mẹtalenirinwo (403) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Nígbà tí Eberi di ẹni ọdún mẹrinlelọgbọn ni ó bí Pelegi. +Eberi tún gbé ojilenirinwo ó dín mẹ́wàá (430) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Pelegi tán, ó tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Nígbà tí Pelegi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu. +Ó tún gbé igba ọdún ó lé mẹsan-an (209) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Bí àwọn eniyan ṣe ń ṣí káàkiri ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n rí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní agbègbè Babiloni, wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ. +Nígbà tí Reu di ẹni ọdún mejilelọgbọn ni ó bí Serugi. +Ó tún gbé igba ọdún ó lé meje (207) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Serugi, ó sì tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Nígbà tí Serugi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori. +Ó tún gbé igba (200) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Nígbà tí Nahori di ẹni ọdún mọkandinlọgbọn ni ó bí Tẹra. +Ó tún gbé igba ọdún ó lé mọkandinlogun (219) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Nígbà tí Tẹra di ẹni aadọrin ọdún ni ó bí Abramu, Nahori, ati Harani. +Àkọsílẹ̀ ìran Tẹra nìyí: Tẹra ni baba Abramu, Nahori ati Harani. Harani sì ni baba Lọti. +Harani kú ṣáájú Tẹra, baba rẹ̀, Uri ìlú rẹ̀, tí ó wà ní ilẹ̀ Kalidea ni ó kú sí. +Abramu ati Nahori ní iyawo, Sarai ni orúkọ iyawo Abramu, orúkọ iyawo ti Nahori sì ni Milika, ọmọbinrin Harani. Harani ni baba Milika ati Isika. +Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á ṣe bíríkì, kí á sì sun wọ́n jiná dáradára.” Bíríkì ni wọ́n lò dípò òkúta, wọ́n sì lo ọ̀dà ilẹ̀ dípò ọ̀rọ̀. +Àgàn ni Sarai, kò bímọ. +Tẹra mú Abramu ọmọ rẹ̀, ati Lọti, ọmọ Harani tíí ṣe ọmọ Tẹra, ati Sarai aya Abramu, ó kó gbogbo wọn jáde kúrò ní Uri ti ilẹ̀ Kalidea, wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé Harani, wọ́n tẹ̀dó sibẹ. +Nígbà tí Tẹra di ẹni igba ọdún ó lé marun-un (205), ó kú ní ilẹ̀ Harani. +Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọ́ ìlú ńlá kan, kí á sì kọ́ ilé ìṣọ́ gíga kan tí orí rẹ̀ yóo kan ojú ọ̀run gbọ̀ngbọ̀n, kí á baà lè di olókìkí, kí á má baà fọ́n káàkiri orí ilẹ̀ ayé.” +OLUWA sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú tí àwọn ọmọ eniyan ń tẹ̀dó ati ilé ìṣọ́ gíga tí wọn ń kọ́. +OLUWA wí pé, “Ọ̀kan ni gbogbo àwọn eniyan wọnyi, èdè kan ṣoṣo ni wọ́n sì ń sọ, wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí wọn yóo ṣe ni, kò sì ní sí ohun kan tí wọn bá dáwọ́lé láti ṣe tí yóo dẹtì fún wọn. +Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á sọ̀kalẹ̀ lọ bá wọn, kí á dà wọ́n ní èdè rú, kí wọn má baà gbọ́ èdè ara wọn mọ́.” +Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fọ́n wọn káàkiri sí gbogbo orílẹ̀ ayé, wọ́n pa ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó tì. +Ìdí nìyí tí wọ́n ṣe pe orúkọ ìlú náà ní Babeli, nítorí níbẹ̀ ni OLUWA ti da èdè gbogbo ayé rú, láti ibẹ̀ ni ó sì ti fọ́n wọn káàkiri gbogbo orílẹ̀ ayé. +Ilé Ìṣọ́ Babeli. +Ní ọjọ́ kan, Ọlọrun sọ fún Abramu pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ, láàrin àwọn ìbátan rẹ, ati kúrò ní ilé baba rẹ lọ sí ilẹ̀ kan tí n óo fi hàn ọ́. +Ní àkókò kan, ìyàn mú gidigidi ní ilẹ̀ Kenaani. Ìyàn náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí Abramu níláti kó lọ sí Ijipti, láti máa gbé ibẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. +Nígbà tí ó ń wo Ijipti lókèèrè, ó sọ fún Sarai aya rẹ̀ pé, “Ṣé ìwọ náà mọ̀ pé arẹwà obinrin ni ọ́, +ati pé bí àwọn ará Ijipti bá ti fi ojú kàn ọ́, wọn yóo wí pé, ‘Iyawo rẹ̀ nìyí’, wọn yóo pa mí, wọn yóo sì dá ọ sí. +Wò ó, wí fún wọn pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wá, kí wọ́n lè ṣe mí dáradára, kí wọ́n má baà tìtorí rẹ pa mí.” +Nígbà tí Abramu wọ Ijipti, àwọn ará Ijipti rí i pé arẹwà obinrin ni aya rẹ̀. +Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Farao rí i, wọ́n pọ́n ọn lójú Farao, wọ́n sì mú un wá sí ààfin rẹ̀. +Nítorí ti Sarai, Farao ṣe Abramu dáradára. Abramu di ẹni tí ó ní ọpọlọpọ aguntan, akọ mààlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, iranṣẹkunrin, iranṣẹbinrin, abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí. +Ṣugbọn OLUWA fi àrùn burúkú bá Farao ati gbogbo ìdílé rẹ̀ jà nítorí Sarai, aya Abramu. +Farao bá pe Abramu, ó bi í pé, “Èéṣe tí o fi ṣe báyìí sí mi? Èéṣe tí o kò fi sọ fún mi pé iyawo rẹ ni Sarai? +Èéṣe tí o fi sọ pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni yín, tí o jẹ́ kí n fi ṣe aya? Iyawo rẹ nìyí, gba nǹkan rẹ, kí o sì máa lọ.” +N óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, n óo bukun ọ, n óo sì sọ orúkọ rẹ di ńlá, tóbẹ́ẹ̀ tí o óo jẹ́ ibukun fún àwọn eniyan. +Farao bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ nípa Abramu, wọ́n sì rí i pé Abramu jáde kúrò nílùú, ati òun ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní. +N óo súre fún àwọn tí wọ́n bá súre fún ọ, bí ẹnikẹ́ni bá sì fi ọ́ bú, n óo fi òun náà bú. Nípasẹ̀ rẹ ni n óo bukun gbogbo ìdílé ayé.” +Bẹ́ẹ̀ ni Abramu ṣe jáde lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún un, Lọti sì bá a lọ. Abramu jẹ́ ẹni ọdún marundinlọgọrin nígbà tí ó jáde kúrò ní Harani. +Abramu mú Sarai iyawo rẹ̀, ati Lọti, ọmọ arakunrin rẹ̀ lọ́wọ́ lọ, ati gbogbo ohun ìní wọn ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n jẹ́ tiwọn ní Harani. Wọ́n jáde, wọ́n gbọ̀nà ilẹ̀ Kenaani.Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Kenaani, +Abramu la ilẹ̀ náà kọjá lọ sí ibi igi Oaku ti More, ní Ṣekemu. Àwọn ará Kenaani ni wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà nígbà náà. +Nígbà náà ni OLUWA fara han Abramu, ó wí pé, “Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA tí ó fara hàn án. +Lẹ́yìn náà Abramu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí orí òkè tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó pàgọ́ sibẹ. Bẹtẹli wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ibùdó rẹ̀, Ai sì wà ní ìhà ìlà oòrùn. Ó tún tẹ́ pẹpẹ mìíràn níbẹ̀, ó sì sin OLUWA. +Abramu ṣá ń lọ sí ìhà gúsù ní agbègbè tí à ń pè ní Nẹgẹbu. +Ọlọrun Pe Abramu. +Bẹ́ẹ̀ ni Abramu ṣe jáde kúrò ní Ijipti, ó pada lọ sí Nẹgẹbu pẹlu aya rẹ̀, ati Lọti ati ohun gbogbo tí ó ní. +Lọti bá gbójú sókè, ó wo gbogbo agbègbè odò Jọdani títí dé Soari, ó rí i pé gbogbo koríko ibẹ̀ ni wọ́n tutù dáradára tí ó dàbí ọgbà OLUWA ati bí ilẹ̀ Ijipti. Ní àkókò náà, OLUWA kò tíì pa ìlú Sodomu ati Gomora run. +Lọti bá yan gbogbo agbègbè odò Jọdani fún ara rẹ̀, ó sì lọ sí ìhà ìlà oòrùn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe takété sí ara wọn. +Abramu ń gbé ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì ń gbé ààrin àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè odò Jọdani, ó pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu. +Àwọn ará Sodomu yìí jẹ́ eniyan burúkú, wọn ń dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA lọpọlọpọ. +Lẹ́yìn tí Lọti ti kúrò lọ́dọ̀ Abramu, OLUWA sọ fún Abramu pé, “Gbé ojú rẹ sókè, kí o wò ó láti ibi tí o wà yìí, títí lọ sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù, tún wò ó lọ sí ìhà ìlà oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀ oòrùn. +Gbogbo ilẹ̀ tí ò ń wò yìí, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún títí lae. +N óo mú kí àwọn ọmọ rẹ pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tí yóo fi jẹ́ pé, àfi ẹni tí ó bá lè ka iye erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóo lè kà wọ́n. +Dìde, kí o rìn jákèjádò ilẹ̀ náà, nítorí pé ìwọ ni n óo fún.” +Nítorí náà, Abramu kó àgọ́ rẹ̀ wá sí ibi igi Oaku ti Mamure, tí ó wà ní Heburoni, níbẹ̀ ni ó ti tẹ́ pẹpẹ fún OLUWA. +Abramu ní dúkìá pupọ ní àkókò yìí, ó ní ẹran ọ̀sìn, fadaka ati wúrà lọpọlọpọ. +Nígbà tí ó yá, ó kúrò ní Nẹgẹbu, ó ń lọ sí Bẹtẹli, ó dé ibi tí ó kọ́kọ́ pàgọ́ sí +láàrin Bẹtẹli ati Ai, níbi pẹpẹ tí ó kọ́kọ́ pa, ibẹ̀ ni ó sì ti sin OLUWA. +Lọti tí ó bá Abramu lọ náà ní ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo mààlúù ati ọpọlọpọ àgọ́ fún ìdílé rẹ̀ ati àwọn iranṣẹ rẹ̀. +Ẹran ọ̀sìn àwọn mejeeji pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ náà kò fi láàyè tó mọ́ fún wọn láti jọ máa gbé pọ̀. +Ìjà sì ń ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn darandaran Abramu ati àwọn ti Lọti. Ní àkókò náà, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi ń gbé ilẹ̀ náà. +Abramu bá sọ fún Lọti pé, “Má jẹ́ kí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, tabi láàrin àwọn darandaran mi ati àwọn tìrẹ. Ṣebí ara kan náà ni wá? +Ilẹ̀ ló lọ jaburata níwájú rẹ yìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí á takété sí ara wa. Bí o bá lọ sí apá òsì, èmi á lọ sí apá ọ̀tún, bí o bá sì lọ sí apá ọ̀tún, èmi á lọ sí apá òsì.” +Abramu ati Lọti Pínyà. +Nígbà kan, àwọn ọba mẹrin kan: Amrafeli, ọba Babiloni, Arioku, ọba Elasari, Kedorilaomeri, ọba Elamu, ati Tidali, ọba Goiimu, +Àfonífojì Sidimu kún fún ihò tí wọ́n ti wa ọ̀dà ilẹ̀. Bí àwọn ọmọ ogun ọba Sodomu ati àwọn ọmọ ogun ọba Gomora ti ń sálọ, àwọn kan ninu wọn jìn sinu àwọn ihò náà, àwọn yòókù sá gun orí òkè lọ. +Àwọn ọ̀tá kó gbogbo ẹrù ati oúnjẹ àwọn ará Sodomu ati Gomora, wọ́n bá tiwọn lọ. +Ọwọ́ wọn tẹ Lọti, ọmọ arakunrin Abramu tí ń gbé ní Sodomu, wọ́n mú un lẹ́rú, wọ́n sì kó gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ. +Nígbà náà ni ẹnìkan tí ó sá àsálà lójú ogun náà wá ròyìn fún Abramu, tí ó jẹ́ Heberu, tí ń gbé lẹ́bàá igi Oaku, ní igbó Mamure, ará Amori. Mamure ati àwọn arakunrin rẹ̀ Eṣikolu ati Aneri bá Abramu dá majẹmu. +Nígbà tí Abramu gbọ́ pé wọ́n ti mú ìbátan òun lẹ́rú, ó kó ọọdunrun ó lé mejidinlogun (318) ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n bí sinu ilé rẹ̀, tí ó sì ti kọ́ ní ogun jíjà, ó lépa àwọn tí wọ́n mú Lọti lẹ́rú lọ títí dé ilẹ̀ Dani. +Ó pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí ní òru ọjọ́ náà. Òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ yí àwọn ọ̀tá náà po, wọ́n ṣí wọn nídìí, wọ́n sì lépa wọn títí dé ìlú Hoba ní apá ìhà àríwá Damasku. +Abramu gba gbogbo ìkógun tí wọ́n kó pada, ó gba Lọti, ìbátan rẹ̀ pẹlu ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, ati àwọn obinrin ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan mìíràn. +Nígbà tí Abramu ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí ó ti ṣẹgun Kedorilaomeri ati àwọn ọba tí wọ́n jọ pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Sodomu jáde lọ pàdé rẹ̀ ní àfonífojì Ṣafe (tí ó tún ń jẹ́, àfonífojì ọba). +Mẹlikisẹdẹki ọba Salẹmu náà mú oúnjẹ ati ọtí waini wá pàdé rẹ̀. Mẹlikisẹdẹki jẹ́ alufaa Ọlọrun Ọ̀gá Ògo. +Ó súre fún Abramu, ó ní:“Kí Ọlọrun Ọ̀gá Ògo,tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun Abramu. +gbógun ti Bera, ọba Sodomu, Birisa ọba Gomora, Ṣinabu, ọba Adima, Ṣemeberi, ọba Seboimu ati ọba ìlú Bela (tí ó tún ń jẹ́, Soari). +Ìyìn sì ni fún Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, ẹni tí ó bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá rẹ.”Abramu bá fún Mẹlikisẹdẹki ní ìdámẹ́wàá gbogbo ìkógun tí ó kó bọ̀. +Ọba Sodomu sọ fún Abramu pé, “Jọ̀wọ́, máa kó gbogbo ìkógun lọ, ṣugbọn dá àwọn eniyan mi pada fún mi.” +Ṣugbọn Abramu dá a lóhùn ó ní: “Mo ti búra fún OLUWA Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, +pé, abẹ́rẹ́ lásán, n kò ní fọwọ́ mi kàn ninu ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, kí o má baà sọ pé ìwọ ni o sọ mí di ọlọ́rọ̀. +N kò ní fọwọ́ mi kan ohunkohun àfi ohun tí àwọn ọmọkunrin tí wọ́n bá mi lọ ti jẹ, ati ìpín tiwọn tí ó kàn wọ́n, ṣugbọn jẹ́ kí Aneri, Eṣikolu ati Mamure kó ìpín tiwọn.” +Gbogbo wọn pa àwọn ọmọ ogun wọn pọ̀ ní àfonífojì Sidimu (tí ó tún ń jẹ́ òkun iyọ̀). +Fún ọdún mejila gbáko ni àwọn ọba maraarun yìí fi sin Kedorilaomeri, ṣugbọn ní ọdún kẹtala, wọ́n dìtẹ̀. +Ní ọdún kẹrinla, Kedorilaomeri ati àwọn ọba tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀ wá, wọ́n ṣẹgun Refaimu tí ó wà ní Aṣiterotu Kanaimu. Bákan náà, wọ́n ṣẹgun àwọn Susimu tí wọ́n wà ní Hamu, àwọn Emimu tí wọ́n wà ní Ṣafe-kiriataimu, +ati àwọn ará Hori ní orí Òkè Seiri, títí dé Eliparani, lẹ́bàá aṣálẹ̀. +Nígbà náà ni wọ́n tó yipada tí wọ́n sì wá sí Enmiṣipati (tí ó tún ń jẹ́ Kadeṣi), wọ́n sì ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amaleki ati ti àwọn ará Amori tí ń gbé Hasasoni Tamari. +Nígbà náà ni ọba Sodomu, ati ọba Gomora jáde lọ, pẹlu ọba Adima, ọba Seboimu, ati ọba Bela, (tí ó tún ń jẹ́, Soari). Wọ́n pa ogun wọn pọ̀ ní àfonífojì Sidimu. +Wọ́n gbógun ti Kedorilaomeri, ọba Elamu, Tidali, ọba Goiimu, Amrafeli, ọba Babiloni ati Arioku, ọba Elasari. Ọba mẹrin dojú kọ ọba marun-un. +Abramu Gba Lọti sílẹ̀. +Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, OLUWA bá Abramu sọ̀rọ̀ lójú ìran, ó ní, “Má bẹ̀rù Abramu, n óo dáàbò bò ọ́, èrè rẹ yóo sì pọ̀ pupọ.” +Ó kó gbogbo wọn wá fún OLUWA, ó là wọ́n sí meji meji, ó sì tẹ́ wọn sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn lọ, ṣugbọn kò la àdàbà ati ẹyẹlé náà. +Nígbà tí àwọn ẹyẹ tí wọ́n máa ń jẹ òkú ẹran rábàbà wá sí ibi tí Abramu to àwọn ẹran náà sí, ó lé wọn. +Nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, oorun bẹ̀rẹ̀ sí kun Abramu, ó sì sun àsùnwọra, jìnnìjìnnì mú un, òkùnkùn biribiri sì bò ó mọ́lẹ̀. +Nígbà náà ni OLUWA sọ fún un pé, “Mọ̀ dájúdájú pé àwọn ọmọ rẹ yóo lọ gbé ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, wọn yóo di ẹrú níbẹ̀, àwọn ará ibẹ̀ yóo sì mú wọn sìn fún irinwo (400) ọdún. +Ṣugbọn n óo mú ìdájọ́ wá sórí orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóo sìn. Àṣẹ̀yìnwá, àṣẹ̀yìnbọ̀, wọn yóo jáde kúrò níbẹ̀ pẹlu ọpọlọpọ dúkìá. +Ìwọ náà yóo dàgbà, o óo di arúgbó, ní ọjọ́ àtisùn rẹ, ikú wọ́ọ́rọ́wọ́ ni o óo kú. +Atọmọdọmọ rẹ kẹrin ni yóo pada wá síhìn-ín, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò tíì kún ojú òṣùnwọ̀n.” +Nígbà tí oòrùn wọ̀, tí ilẹ̀ sì ṣú, kòkò iná tí ó ń rú èéfín ati ìtùfù tí ń jò lálá kan kọjá láàrin àwọn ẹran tí Abramu tò sílẹ̀. +Ní ọjọ́ náà ni OLUWA bá a dá majẹmu, ó sọ pé, “Àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ijipti títí dé odò ńlá nì, àní odò Yufurate, +ilẹ̀ àwọn ará Keni, ti àwọn ará Kenisi, ti àwọn ará Kadimoni, +Ṣugbọn Abramu dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun, kí ni o óo fún mi, n kò tíì bímọ títí di ìsinsìnyìí! Ṣé Elieseri ará Damasku yìí ni yóo jẹ́ àrólé mi ni? +ti àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Perisi, ti àwọn ará Refaimu, +ti àwọn ará Amori, ti àwọn ará Kenaani, ti àwọn ará Girigaṣi ati ti àwọn ará Jebusi.” +O kò fún mi lọ́mọ, ẹrú tí wọ́n bí ninu ilé mi ni yóo di àrólé mi!” +OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe ọkunrin yìí ni yóo jẹ́ àrólé rẹ, ọmọ bíbí inú rẹ ni yóo jẹ́ àrólé rẹ.” +OLUWA bá mú un jáde, ó sì sọ fún un pé, “Wo ojú ọ̀run, kí o ka gbogbo ìràwọ̀ tí ó wà níbẹ̀ bí o bá lè kà wọ́n.” OLUWA bá sọ fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ yóo ṣe pọ̀ tó.” +Abramu gba OLUWA gbọ́, OLUWA sì kà á sí olódodo. +Ó sọ fún un pé “Èmi ni OLUWA tí ó mú ọ jáde láti ìlú Uri, ní ilẹ̀ Kalidea, láti fi ilẹ̀ yìí fún ọ ní ohun ìní.” +Ṣugbọn Abramu bèèrè pé, “OLUWA Ọlọrun, báwo ni n óo ṣe mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóo jẹ́ tèmi?” +OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “Mú ẹgbọ̀rọ̀ abo mààlúù ọlọ́dún mẹta kan, ati ewúrẹ́ ọlọ́dún mẹta kan, ati àgbò ọlọ́dún mẹta kan, ati àdàbà kan ati ọmọ ẹyẹlé kan wá.” +Majẹmu Ọlọrun pẹlu Abramu. +Sarai, aya Abramu, kò bímọ fún un. Ṣugbọn ó ní ẹrubinrin ará Ijipti kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hagari. +Angẹli OLUWA náà tún wí fún un pé, “N óo sọ atọmọdọmọ rẹ di pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kì yóo le kà wọ́n tán. +Wò ó! oyún tí ó wà ninu rẹ, ọkunrin ni o óo fi bí, o óo sọ ọmọ náà ní Iṣimaeli, nítorí OLUWA ti rí gbogbo ìyà tí ń jẹ ọ́. +Oníjàgídíjàgan ẹ̀dá ni yóo jẹ́, bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó, yóo máa bá gbogbo eniyan jà, gbogbo eniyan yóo sì máa bá a jà, títa ni yóo sì takété sí àwọn ìbátan rẹ̀.” +Nítorí náà, ó pe orúkọ OLUWA tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní “Ìwọ ni Ọlọrun tí ń rí nǹkan.” Nítorí ó wí pé, “Ṣé nítòótọ́ ni mo rí Ọlọrun, tí mo sì tún wà láàyè?” +Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe orúkọ kànga náà ní Beeri-lahai-roi, ó wà láàrin Kadeṣi ati Beredi. +Hagari bí ọmọkunrin kan fún Abramu, Abramu sì sọ ọmọ náà ní Iṣimaeli. +Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹrindinlaadọrun nígbà tí Hagari bí Iṣimaeli fún un. +Ní ọjọ́ kan, Sarai pe Abramu, ó sọ fún un pé, “Ṣé o rí i pé OLUWA kò jẹ́ kí n bímọ, nítorí náà bá ẹrubinrin mi yìí lòpọ̀, ó le jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni n óo ti ní ọmọ.” Abramu sì gba ọ̀rọ̀ Sarai aya rẹ̀. +Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti dé ilẹ̀ Kenaani ni Sarai, aya rẹ̀ fa Hagari, ará Ijipti, ẹrubinrin rẹ̀ fún un, láti fi ṣe aya. +Abramu bá Hagari lòpọ̀, Hagari sì lóyún. Nígbà tí ó rí i pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú tẹmbẹlu Sarai, oluwa rẹ̀. +Sarai bá sọ fún Abramu pé, “Ibi tí Hagari ń ṣe sí mi yìí yóo dà lé ọ lórí. Èmi ni mo fa ẹrubinrin mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó rí i pé òun lóyún tán, mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́ lójú rẹ̀. OLUWA ni yóo ṣe ìdájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ.” +Ṣugbọn Abramu dá a lóhùn pé, “Ṣebí ìkáwọ́ rẹ ni ẹrubinrin rẹ wà, ṣe é bí ó bá ti wù ọ́.” Sarai bá bẹ̀rẹ̀ sí fòòró ẹ̀mí Hagari, Hagari sì sá kúrò nílé. +Angẹli OLUWA rí i lẹ́bàá orísun omi kan tí ó wà láàrin aṣálẹ̀ lọ́nà Ṣuri. +Ó pè é, ó ní, “Hagari, ẹrubinrin Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo ni o sì ń lọ?” Hagari dáhùn pé, “Mò ń sálọ fún Sarai, oluwa mi ni.” +Angẹli OLUWA náà wí fún un pé, “Pada tọ oluwa rẹ lọ, kí o sì tẹríba fún un.” +Hagari ati Iṣimaeli. +Nígbà tí Abramu di ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un, OLUWA farahàn án, ó sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa gbọ́ tèmi, kí o sì jẹ́ pípé. +Majẹmu náà tí ó wà láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ, tí ẹ gbọdọ̀ pamọ́ nìyí, gbogbo àwọn ọmọkunrin yín gbọdọ̀ kọlà abẹ́. +Ilà abẹ́ tí ẹ gbọdọ̀ kọ yìí ni yóo jẹ́ àmì majẹmu tí ó wà láàrin mi pẹlu yín. +Gbogbo ọmọkunrin tí ó bá ti pé ọmọ ọjọ́ mẹjọ láàrin yín gbọdọ̀ kọlà abẹ́, gbogbo ọmọkunrin ninu ìran yín, kì báà ṣe èyí tí a bí ninu ilé yín, tabi ẹrú tí ẹ rà lọ́wọ́ àjèjì, tí kì í ṣe ìran yín, +gbogbo ọmọ tí ẹ bí ninu ilé yín, ati ẹrú tí ẹ fi owó yín rà gbọdọ̀ kọlà abẹ́. Èyí yóo jẹ́ kí majẹmu mi wà lára yín, yóo sì jẹ́ majẹmu ayérayé. +Gbogbo ọkunrin tí kò bá kọlà abẹ́ ni a óo yọ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé ó ti ba majẹmu mi jẹ́.” +Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai aya rẹ, má ṣe pè é ní Sarai mọ́, Sara ni orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́. +N óo bukun un, n óo sì fún ọ ní ọmọkunrin kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, n óo bukun un, yóo sì di ìyá ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo wà lára atọmọdọmọ rẹ̀.” +Nígbà náà ni Abrahamu dojúbolẹ̀, ó búsẹ́rìn-ín, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Ọkunrin tí ó ti di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ha tún lè bímọ bí? Sara, tí ó ti di ẹni aadọrun-un ọdún ha tún lè bímọ bí?” +Abrahamu bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣá ti bá mi dá Iṣimaeli yìí sí.” +Ọlọrun dá a lóhùn, pé, “Rárá o, àní, Sara, aya rẹ, yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo sọ ọmọ náà ní Isaaki. N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé fún atọmọdọmọ rẹ̀. +N óo bá ọ dá majẹmu kan, tí yóo wà láàrin èmi pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ lọpọlọpọ.” +Ní ti Iṣimaeli, mo ti gbọ́ ìbéèrè rẹ, wò ó, n óo bukun òun náà, n óo sì fún un ní ọpọlọpọ ọmọ ati ọmọ ọmọ, yóo jẹ́ baba fún àwọn ọba mejila, n óo sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá. +Ṣugbọn n óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu Isaaki, tí Sara yóo bí fún ọ ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀.” +Nígbà tí Ọlọrun bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, ó gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. +Abrahamu bá mú Iṣimaeli ọmọ rẹ̀, ati gbogbo àwọn ẹrukunrin tí wọ́n bí ninu ilé rẹ̀ ati àwọn tí ó fi owó rẹ̀ rà, àní gbogbo ọkunrin tí ó wà ninu ìdílé Abrahamu, ó sì kọ gbogbo wọn ní ilà abẹ́ ní ọjọ́ náà, bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un. +Abrahamu jẹ́ ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un nígbà tí ó kọ ilà abẹ́. +Iṣimaeli ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọdún mẹtala nígbà tí òun náà kọlà abẹ́. +Ní ọjọ́ náà gan-an ni Abrahamu ati Iṣimaeli ọmọ rẹ̀ kọlà abẹ́, +ati gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀, ati àwọn tí wọ́n bí sinu ilé rẹ̀, ati àwọn tí wọ́n fi owó rà, gbogbo wọn ni wọ́n kọ nílà abẹ́ pẹlu rẹ̀. +Abramu bá dojúbolẹ̀, Ọlọrun tún wí fún un pé, +“Majẹmu tí mo bá ọ dá kò yẹ̀ rárá: O óo jẹ́ baba ńlá fún ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè. +Orúkọ rẹ kò ní jẹ́ Abramu mọ́, Abrahamu ni o óo máa jẹ́, nítorí mo ti sọ ọ́ di baba ńlá fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè. +N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ, n óo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo sì ti ara rẹ jáde.” +“N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ. Majẹmu náà yóo wà títí ayérayé pé, èmi ni n óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ ati ti atọmọdọmọ rẹ. +N óo fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ náà tí o ti jẹ́ àlejò yìí yóo di ìní rẹ títí ayérayé ati ti atọmọdọmọ rẹ, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn!” +Ọlọrun tún sọ fún Abrahamu pé, “Ìwọ pàápàá gbọdọ̀ pa majẹmu mi mọ́, ìwọ ati atọmọdọmọ rẹ láti ìrandíran wọn. +Ilà Abẹ́ Kíkọ, Àmì Majẹmu Ọlọrun. +Ní ọ̀sán gangan ọjọ́ kan, OLUWA fara han Abrahamu bí ó ti jókòó ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, lẹ́bàá igi Oaku ti Mamure. +Ọ̀kan ninu àwọn àlejò náà wí pé, “Dájúdájú, n óo pada tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara, aya rẹ yóo bí ọmọkunrin kan.”Sara fetí mọ́ ògiri lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ lẹ́yìn ibi tí àwọn àlejò náà wà, ó ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ. +Abrahamu ati Sara ti di àgbàlagbà ní àkókò yìí, ogbó ti dé sí wọn, ọjọ́ ti pẹ́ tí Sara ti rí nǹkan oṣù rẹ̀ kẹ́yìn. +Nítorí náà, nígbà tí Sara gbọ́ pé òun óo bímọ, ó rẹ́rìn-ín sinu ara rẹ̀, ó ní, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó, tí ọkọ mi náà sì ti di arúgbó, ǹjẹ́ mo tilẹ̀ tún lè gbádùn oorun ọmọ bíbí?” +OLUWA bi Abrahamu pé, “Èéṣe tí Sara fi rẹ́rìn-ín, tí ó wí pé, ṣé lóòótọ́ ni òun óo bímọ lẹ́yìn tí òun ti darúgbó? +Ṣé ohun kan wà tí ó ṣòro fún OLUWA ni? Nígbà tí àkókò bá tó, n óo pada wá sọ́dọ̀ rẹ níwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara yóo bí ọmọkunrin kan.” +Ẹ̀rù ba Sara, ó sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín. OLUWA sọ pé, “Má purọ́! o rẹ́rìn-ín.” +Nígbà tí àwọn ọkunrin náà kúrò lọ́dọ̀ Abrahamu, wọ́n dojú kọ ọ̀nà Sodomu, Abrahamu bá wọn lọ láti sìn wọ́n dé ọ̀nà. +OLUWA sọ pé, “Mo ha gbọdọ̀ fi ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí pamọ́ fún Abrahamu, +nígbà tí ó jẹ́ pé ìran rẹ̀ yóo di orílẹ̀-èdè ńlá tí yóo lágbára, ati pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni n óo bukun gbogbo orílẹ̀-èdè? +N kò ní fi pamọ́ fún un, nítorí pé mo ti yàn án, kí ó lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo ará ilé rẹ̀, láti máa pa ìlànà èmi OLUWA mọ́, ati kí wọ́n sì jẹ́ olódodo ati olóòótọ́, kí èmi OLUWA lè mú ìlérí mi ṣẹ fún Abrahamu.” +Bí ó ti gbójú sókè, bẹ́ẹ̀ ni ó rí àwọn ọkunrin mẹta kan, wọ́n dúró ní ọ̀kánkán níwájú rẹ̀. Bí ó ti rí wọn, ó sáré lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ láti kí wọn. +OLUWA bá sọ pé; “Ẹ̀sùn tí àwọn eniyan fi ń kan Sodomu ati Gomora ti pọ̀ jù, ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jáì! +Mo fẹ́ lọ fi ojú ara mi rí i, kí n fi mọ̀, bóyá gbogbo bí mo ti ń gbọ́ nípa wọn ni wọ́n ń ṣe nítòótọ́.” +Àwọn ọkunrin náà bá kúrò níbẹ̀, wọ́n gba ọ̀nà Sodomu lọ, ṣugbọn Abrahamu tún dúró níwájú OLUWA níbẹ̀. +Abrahamu bá súnmọ́ OLUWA, ó wí pé, “O ha gbọdọ̀ pa àwọn olódodo run pẹlu àwọn eniyan burúkú bí? +A kì í bàá mọ̀, bí aadọta olódodo bá wà ninu ìlú náà, ṣé o óo pa ìlú náà run, o kò sì ní dá a sí nítorí aadọta olódodo tí ó wà ninu rẹ̀? +Kí á má rí i pé o ṣe irú ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀! Kí o pa olódodo run pẹlu àwọn eniyan burúkú? Ṣé kò ní sí ìyàtọ̀ láàrin ìpín àwọn eniyan burúkú ati ti àwọn olódodo ni? A kò gbọdọ̀ gbọ́ ọ. Ìwọ onídàájọ́ gbogbo ayé kò ha ní ṣe ẹ̀tọ́ bí?” +OLUWA dáhùn, ó ní, “Bí mo bá rí aadọta olódodo ninu ìlú Sodomu, n óo dá gbogbo ìlú náà sí nítorí tiwọn.” +Abrahamu tún sọ fún OLUWA pé, “Jọ̀wọ́, dárí àfojúdi mi jì mí, èmi eniyan lásán, nítorí n kò ní ẹ̀tọ́ láti bá ìwọ OLUWA jiyàn? +Ṣugbọn, ó ṣeéṣe pé aadọta tí mo wí lè dín marun-un, ṣé nítorí eniyan marun-un tí ó dín, o óo pa ìlú náà run?” OLUWA dáhùn pé, “Bí mo bá rí olódodo marundinlaadọta n kò ní pa ìlú náà run.” +Ó tún bèèrè pé, “Bí a bá rí ogoji ńkọ́?” OLUWA tún dáhùn, ó ní, “N kò ní pa á run nítorí ogoji eniyan náà.” +Ó wí pé, “Ẹ̀yin oluwa mi, bí inú yín bá dùn sí mi, ẹ jọ̀wọ́, ẹ má kọjá lọ bẹ́ẹ̀ láìdúró díẹ̀ lọ́dọ̀ èmi iranṣẹ yín! +Ó bá tún wí pé, “OLUWA, jọ̀wọ́ má bínú sí mi, bí a bá rí ọgbọ̀n eniyan ńkọ́?” OLUWA dáhùn pé, “Bí mo bá rí ọgbọ̀n olódodo, n kò ní pa ìlú náà run.” +Ó tún dáhùn pé “Jọ̀wọ́ dárí àfojúdi mi jì mí nítorí ọ̀rọ̀ mi, bí a bá rí ogún eniyan ńkọ́?” OLUWA tún dáhùn pé, “Nítorí ti ogún eniyan, n kò ní pa á run.” +Abrahamu tún dáhùn pé, “OLUWA, jọ̀wọ́ má bínú sí mi, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré yìí ni ó kù tí n óo sọ̀rọ̀. Bí a bá rí eniyan mẹ́wàá ńkọ́?”OLUWA tún dá a lóhùn pé, “N kò ní pa á run nítorí ti eniyan mẹ́wàá.” +Nígbà tí OLUWA bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, ó bá tirẹ̀ lọ, Abrahamu náà bá pada sí ilé rẹ̀. +Ẹ jẹ́ kí wọ́n bu omi wá kí ẹ fi ṣan ẹsẹ̀, kí ẹ sì sinmi díẹ̀ lábẹ́ igi níhìn-ín. +Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti yà lọ́dọ̀ èmi iranṣẹ yín, ẹ kúkú jẹ́ kí n tètè tọ́jú oúnjẹ díẹ̀ fún yín láti jẹ, bí ẹ bá tilẹ̀ wá fẹ́ máa lọ nígbà náà, kò burú.”Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, lọ ṣe bí o ti wí.” +Abrahamu yára wọ inú àgọ́ tọ Sara lọ, ó sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ tètè tọ́jú ìwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára mẹta, bá mi yára pò ó, kí o fi ṣe àkàrà.” +Abrahamu tún yára lọ sinu agbo mààlúù rẹ̀, ó mú ọ̀dọ́ mààlúù kan tí ó lọ́ràá dáradára, ó fà á fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó ní kí wọ́n yára pa á, kí wọ́n sì sè é. +Ó mú wàràǹkàṣì, ati omi wàrà, ati ẹran ọ̀dọ́ mààlúù tí wọ́n sè, ó gbé wọn kalẹ̀ fún àwọn àlejò náà, ó sì dúró tì wọ́n bí wọ́n ti ń jẹun lábẹ́ igi. +Nígbà tí wọ́n jẹun tán, wọ́n bi í pé, “Níbo ni Sara aya rẹ wà?”Ó dá wọn lóhùn pé, “Ó wà ninu àgọ́.” +Ọlọrun Ṣèlérí Ọmọkunrin Kan fún Abrahamu. +Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn angẹli meji náà dé ìlú Sodomu, Lọti sì jókòó ní ẹnubodè ìlú náà. Bí ó ti rí wọn, ó dìde lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ láti kí wọn. +Àwọn àjèjì náà bá fa Lọti wọlé, wọ́n ti ìlẹ̀kùn, +wọ́n sì bu ìfọ́jú lu àwọn ọkunrin tí wọ́n ṣù bo ìlẹ̀kùn lóde, àtèwe, àtàgbà wọn, wọ́n wá ojú ọ̀nà títí tí agara fi dá wọn. +Àwọn àlejò náà pe Lọti, wọ́n sọ fún un pé, “Bí o bá ní ẹnikẹ́ni ninu ìlú yìí, ìbáà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin tabi ọkọ àwọn ọmọ rẹ, tabi ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ tìrẹ ninu ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò níhìn-ín, +nítorí pé a ti ṣetán láti pa ìlú yìí run, nítorí ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kan àwọn ará ìlú yìí ti pọ̀ níwájú OLUWA, OLUWA sì ti rán wa láti pa á run.” +Lọti bá jáde lọ bá àwọn ọkunrin tí wọ́n fẹ́ àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji sọ́nà, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ dìde, ẹ jáde kúrò ninu ìlú yìí nítorí OLUWA fẹ́ pa á run.” Ṣugbọn àwàdà ni ọ̀rọ̀ náà jọ létí wọn. +Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú, àwọn angẹli náà rọ Lọti pé, “Dìde, mú aya rẹ ati àwọn ọmọ rẹ mejeeji tí wọ́n wà níhìn-ín kí o sì jáde, kí o má baà parun pẹlu ìlú yìí.” +Ṣugbọn nígbà tí Lọti bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ra, àwọn angẹli meji náà mú òun ati aya rẹ̀, pẹlu àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji, wọ́n kó wọn jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, nítorí pé OLUWA ṣàánú Lọti. +Nígbà tí wọ́n kó wọn jáde tán, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín; ẹ má ṣe wo ẹ̀yìn rárá, ẹ má sì ṣe dúró níbikíbi ní àfonífojì yìí, ẹ sá gun orí òkè lọ, kí ẹ má baà parun.” +Ṣugbọn Lọti wí fún wọn pé, “Áà! Rárá! oluwa mi. +Èmi iranṣẹ yín ti rí ojurere lọ́dọ̀ yín, ẹ sì ti ṣe mí lóore ńlá nípa gbígba ẹ̀mí mi là, ṣugbọn n kò ní le sálọ sí orí òkè, kí ijamba má baà ká mi mọ́ ojú ọ̀nà, kí n sì k��. +Ó ní, “Ẹ̀yin oluwa mi, ẹ jọ̀wọ́ ẹ yà sí ilé èmi iranṣẹ yín, kí ẹ ṣan ẹsẹ̀ yín, kí ẹ sì sùn ní alẹ́ yìí, bí ó bá di ìdájí ọ̀la, kí ẹ máa bá tiyín lọ.” Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “Ó tì o! ìta gbangba láàrin ìlú ni a fẹ́ sùn.” +Ẹ wò ó, ìlú tí ó wà lọ́hùn-ún nì súnmọ́ tòsí tó láti sálọ, ó sì tún jẹ́ ìlú kékeré. Ẹ jẹ́ kí n sálọ sibẹ, ṣebí ìlú kékeré ni? Ẹ̀mí mi yóo sì là.” +OLUWA dáhùn pé, “Ó dára, mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ, n kò ní pa ìlú náà run. +Ṣe kíá, kí o sálọ sibẹ, nítorí n kò lè ṣe ohunkohun, títí tí o óo fi dé ibẹ̀.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ìlú náà ní Soari. +Oòrùn ti yọ nígbà tí Lọti dé Soari. +OLUWA bá rọ òjò imí ọjọ́ ati iná láti ọ̀run wá sórí Sodomu ati Gomora, +ó sì pa ìlú náà run ati gbogbo àfonífojì náà. Ó pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé àwọn ìlú náà run, ati gbogbo ohun tí ó hù lórí ilẹ̀. +Ṣugbọn aya Lọti tí ó wà lẹ́yìn ọkọ rẹ̀ wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ̀n iyọ̀. +Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Abrahamu lọ sí ibi tí ó ti dúró níwájú OLUWA, +ó wo ìhà ibi tí Sodomu ati Gomora wà, ati gbogbo àfonífojì náà, ó rí i pé gbogbo rẹ̀ ń yọ èéfín bí iná ìléru ńlá. +Ọlọrun ranti Abrahamu, nígbà tí ó pa àwọn ìlú tí ó wà ní àfonífojì náà, níbi tí Lọti ń gbé run, ó yọ Lọti jáde kúrò ninu ìparun. +Ṣugbọn ó rọ̀ wọ́n gidigidi, wọ́n bá yà sí ilé rẹ̀, ó se àsè fún wọn, ó ṣe àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà sí, wọ́n sì jẹun. +Nígbà tí ó yá, Lọti jáde kúrò ní Soari, nítorí ẹ̀rù ń bà á láti máa gbé ibẹ̀, òun ati àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji bá kó lọ sí orí òkè, wọ́n sì ń gbé inú ihò kan níbẹ̀. +Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò, ó ní, “Baba wa ń darúgbó lọ, kò sì sí ọkunrin kan tí yóo fẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn eniyan. +Wò ó! Jẹ́ kí á mú baba wa mu ọtí àmupara, kí á sì sùn lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè bá wa lòpọ̀, kí á le tipasẹ̀ rẹ̀ bímọ.” +Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún baba wọn ní ọtí mu ní alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àkọ́bí wọlé lọ, ó sì mú kí baba wọ́n bá òun lòpọ̀, baba wọn kò mọ ìgbà tí ó sùn ti òun, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìgbà tí ó dìde. +Ní ọjọ́ keji, èyí àkọ́bí sọ fún àbúrò pé, “Èmi ni mo sùn lọ́dọ̀ baba wa lánàá, jẹ́ kí á tún mú kí ó mu ọtí àmupara lálẹ́ òní, kí ìwọ náà lè wọlé tọ̀ ọ́ lọ, kí ó lè bá ọ lòpọ̀, kí á sì lè bímọ nípasẹ̀ baba wa.” +Wọ́n mú kí baba wọn mu ọtí waini ní alẹ́ ọjọ́ náà pẹlu, èyí àbúrò lọ sùn tì í, baba wọn kò mọ ìgbà tí ó sùn ti òun, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìgbà tí ó dìde. +Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lọti mejeeji ṣe lóyún fún baba wọn. +Èyí àkọ́bí bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Moabu, òun ni baba ńlá àwọn ẹ̀yà Moabu títí di òní olónìí. +Èyí àbúrò náà bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Bẹnami, òun ni baba ńlá àwọn ẹ̀yà Amoni títí di òní olónìí. +Ṣugbọn kí àwọn àlejò náà tó sùn, gbogbo àwọn ọkunrin ìlú Sodomu ti dé, àtèwe, àtàgbà, gbogbo wọn dé láìku ẹnìkan, wọ́n yí ilé Lọti po. +Wọ́n pe Lọti, wọ́n ní, “Níbo ni àwọn ọkunrin tí wọ́n dé sọ́dọ̀ rẹ ní alẹ́ yìí wà? Kó wọn jáde fún wa, a fẹ́ bá wọn lòpọ̀.” +Lọti bá jáde sí wọn, ó ti ìlẹ̀kùn mọ́ àwọn àlejò sinu ilé, +ó bẹ̀ wọ́n pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ má hu irú ìwà burúkú yìí. +Ẹ wò ó, mo ní àwọn ọmọbinrin meji tí wọn kò tíì mọ ọkunrin, ẹ jẹ́ kí n kó wọn jáde fún yín, kí ẹ ṣe wọ́n bí ó ti wù yín, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi àwọn ọkunrin wọnyi sílẹ̀, nítorí pé inú ilé mi ni wọ́n wọ̀ sí.” +Wọ́n dáhùn pé, “Yàgò lọ́nà fún wa, ṣebí àjèjì ni ọ́ ní ilẹ̀ yìí? Ta ni ọ́ tí o fi ń sọ ohun tí ó yẹ kí á ṣe fún wa? Bí o kò bá ṣọ́ra, a óo ṣe sí ọ ju bí a ti fẹ́ ṣe sí wọn lọ.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ti Lọti mọ́ ara ìlẹ̀kùn títí ìlẹ̀kùn fi fẹ́rẹ̀ já. +Ìwà Ẹ̀ṣẹ̀ Sodomu. +Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe parí dídá ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn. +Odò kan ṣàn jáde láti inú ọgbà Edẹni tí omi rẹ̀ máa ń mú kí ọgbà náà rin. Lẹ́yìn tí odò yìí ṣàn kọjá ọgbà Edẹni, ó pín sí mẹrin. +Orúkọ odò kinni ni Piṣoni. Òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà wà. +Wúrà ilẹ̀ náà dára. Turari olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní bedeliumu, ati òkúta olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní onikisi wà níbẹ̀ pẹlu. +Orúkọ odò keji ni Gihoni, òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. +Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó ṣàn lọ sí apá ìlà oòrùn Asiria. Ẹkẹrin ni odò Yufurate. +OLUWA Ọlọrun fi ọkunrin tí ó dá sinu ọgbà Edẹni, kí ó máa ro ó, kí ó sì máa tọ́jú rẹ̀. +Ó pàṣẹ fún ọkunrin náà, ó ní, “O lè jẹ ninu èso gbogbo igi tí ó wà ninu ọgbà yìí, +ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso igi ìmọ̀ ibi ati ire. Ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ ni o óo kú.” +Lẹ́yìn náà OLUWA Ọlọrun sọ pé, “Kò dára kí ọkunrin náà nìkan dá wà, n óo ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, tí yóo dàbí rẹ̀.” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun bu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ gbogbo ẹranko ati gbogbo ẹyẹ. Ó kó wọn tọ ọkunrin náà wá, láti mọ orúkọ tí yóo sọ olukuluku wọn. Orúkọ tí ó sì sọ wọ́n ni wọ́n ń jẹ́. +Ní ọjọ́ keje, Ọlọrun parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe, ó sì sinmi ní ọjọ́ náà. +Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà sọ gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ẹyẹ ati ẹranko ní orúkọ, ṣugbọn ninu gbogbo wọn, kò sí ọ̀kan tí ó le jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí ó yẹ ẹ́. +Nígbà náà OLUWA Ọlọrun kun ọkunrin yìí ní oorun àsùnwọra, nígbà tí ó sùn, Ọlọrun yọ ọ̀kan ninu àwọn egungun ìhà rẹ̀, ó sì fi ẹran dípò rẹ̀. +Ó fi egungun náà mọ obinrin kan, ó sì mú un tọ ọkunrin náà lọ. +Ọkunrin náà bá wí pé,“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ẹni tí ó dàbí mi,ẹni tí a mú jáde láti inú egungun ati ẹran ara mi;obinrin ni yóo máa jẹ́,nítorí pé láti ara ọkunrin ni a ti mú un jáde.” +Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, tí yóo sì faramọ́ aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo sì di ara kan ṣoṣo. +Ọkunrin náà ati obinrin náà wà ní ìhòòhò, ojú kò sì tì wọ́n. +Ó súre fún ọjọ́ keje yìí, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ọjọ́ náà ni ó sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe bọ̀. +Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe dá ọ̀run ati ayé.Nígbà tí OLUWA Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, +kò tíì sí ohun ọ̀gbìn kankan lórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ewéko kankan kò tíì hù jáde nítorí pé OLUWA Ọlọrun kò tíì rọ òjò sórí ilẹ̀, kò sì tíì sí eniyan láyé tí yóo máa ro ilẹ̀. +Ṣugbọn omi kan a máa ru jáde láti inú ilẹ̀ láti mú kí gbogbo ilẹ̀ rin. +Nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun bù ninu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ eniyan. Ó mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, eniyan sì di ẹ̀dá alààyè. +OLUWA Ọlọrun ṣe ọgbà kan sí Edẹni, ní ìhà ìlà oòrùn, ó fi eniyan tí ó mọ sinu rẹ̀. +Láti inú ilẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun ti mú kí oríṣìíríṣìí igi hù jáde ninu ọgbà náà, tí wọ́n dùn ún wò, tí wọ́n sì dára fún jíjẹ. Igi ìyè wà láàrin ọgbà náà, ati igi ìmọ̀ ibi ati ire. +Ọgbà Edẹni. +Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe parí dídá ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn. +Odò kan ṣàn jáde láti inú ọgbà Edẹni tí omi rẹ̀ máa ń mú kí ọgbà náà rin. Lẹ́yìn tí odò yìí ṣàn kọjá ọgbà Edẹni, ó pín sí mẹrin. +Orúkọ odò kinni ni Piṣoni. Òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà wà. +Wúrà ilẹ̀ náà dára. Turari olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní bedeliumu, ati òkúta olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní onikisi wà níbẹ̀ pẹlu. +Orúkọ odò keji ni Gihoni, òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. +Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó ṣàn lọ sí apá ìlà oòrùn Asiria. Ẹkẹrin ni odò Yufurate. +OLUWA Ọlọrun fi ọkunrin tí ó dá sinu ọgbà Edẹni, kí ó máa ro ó, kí ó sì máa tọ́jú rẹ̀. +Ó pàṣẹ fún ọkunrin náà, ó ní, “O lè jẹ ninu èso gbogbo igi tí ó wà ninu ọgbà yìí, +ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso igi ìmọ̀ ibi ati ire. Ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ ni o óo kú.” +Lẹ́yìn náà OLUWA Ọlọrun sọ pé, “Kò dára kí ọkunrin náà nìkan dá wà, n óo ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, tí yóo dàbí rẹ̀.” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun bu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ gbogbo ẹranko ati gbogbo ẹyẹ. Ó kó wọn tọ ọkunrin náà wá, láti mọ orúkọ tí yóo sọ olukuluku wọn. Orúkọ tí ó sì sọ wọ́n ni wọ́n ń jẹ́. +Ní ọjọ́ keje, Ọlọrun parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe, ó sì sinmi ní ọjọ́ náà. +Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà sọ gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ẹyẹ ati ẹranko ní orúkọ, ṣugbọn ninu gbogbo wọn, kò sí ọ̀kan tí ó le jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí ó yẹ ẹ́. +Nígbà náà OLUWA Ọlọrun kun ọkunrin yìí ní oorun àsùnwọra, nígbà tí ó sùn, Ọlọrun yọ ọ̀kan ninu àwọn egungun ìhà rẹ̀, ó sì fi ẹran dípò rẹ̀. +Ó fi egungun náà mọ obinrin kan, ó sì mú un tọ ọkunrin náà lọ. +Ọkunrin náà bá wí pé,“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ẹni tí ó dàbí mi,ẹni tí a mú jáde láti inú egungun ati ẹran ara mi;obinrin ni yóo máa jẹ́,nítorí pé láti ara ọkunrin ni a ti mú un jáde.” +Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, tí yóo sì faramọ́ aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo sì di ara kan ṣoṣo. +Ọkunrin náà ati obinrin náà wà ní ìhòòhò, ojú kò sì tì wọ́n. +Ó súre fún ọjọ́ keje yìí, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ọjọ́ náà ni ó sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe bọ̀. +Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe dá ọ̀run ati ayé.Nígbà tí OLUWA Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, +kò tíì sí ohun ọ̀gbìn kankan lórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ewéko kankan kò tíì hù jáde nítorí pé OLUWA Ọlọrun kò tíì rọ òjò sórí ilẹ̀, kò sì tíì sí eniyan láyé tí yóo máa ro ilẹ̀. +Ṣugbọn omi kan a máa ru jáde láti inú ilẹ̀ láti mú kí gbogbo ilẹ̀ rin. +Nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun bù ninu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ eniyan. Ó mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, eniyan sì di ẹ̀dá alààyè. +OLUWA Ọlọrun ṣe ọgbà kan sí Edẹni, ní ìhà ìlà oòrùn, ó fi eniyan tí ó mọ sinu rẹ̀. +Láti inú ilẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun ti mú kí oríṣìíríṣìí igi hù jáde ninu ọgbà náà, tí wọ́n dùn ún wò, tí wọ́n sì dára fún jíjẹ. Igi ìyè wà láàrin ọgbà náà, ati igi ìmọ̀ ibi ati ire. +Ọgbà Edẹni. +Láti ibẹ̀ ni Abrahamu ti lọ sí agbègbè Nẹgẹbu, ó sì ń gbé Gerari, ní ààrin Kadeṣi ati Ṣuri. +Ó bi Abrahamu pé, “Kí ni èrò rẹ gan-an, tí o fi ṣe ohun tí o ṣe yìí?” +Abrahamu dáhùn, ó ní, “Ohun tí ó mú mi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé, mo rò pé kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun níhìn-ín rárá ni, ati pé wọn yóo tìtorí aya mi pa mí. +Ati pé, arabinrin mi ni nítòótọ́, bí ó ṣe jẹ́ nìyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìyá kan náà ni ó bí wa, ọmọ baba kan ni wá kí ó tó di aya mi. +Nígbà tí Ọlọrun mú kí n máa káàkiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Oore kan tí o lè ṣe fún mi nìyí: níbi gbogbo tí a bá dé, wí fún wọn pé, arakunrin rẹ ni mí.’ ” +Abimeleki mú aguntan ati mààlúù ati ẹrukunrin ati ẹrubinrin, ó kó wọn fún Abrahamu, ó sì dá Sara, aya rẹ̀, pada fún un. +Abimeleki tún wí fún un pé, “Wo gbogbo ilẹ̀ yìí, èmi ni mo ni ín, yan ibi tí ó bá wù ọ́ láti gbé.” +Ó wí fún Sara náà pé, “Mo ti kó ẹgbẹrun (1,000) owó fadaka fún arakunrin rẹ, èyí ni láti wẹ̀ ọ́ mọ́ lójú gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ, nisinsinyii, o ti gba ìdáláre lójú gbogbo eniyan.” +Abrahamu bá gbadura sí Ọlọrun, Ọlọrun sì wo Abimeleki sàn ati aya rẹ̀ ati àwọn ẹrubinrin rẹ̀, tí wọ́n fi lè bímọ, +nítorí pé Ọlọrun ti sé gbogbo àwọn obinrin ilé Abimeleki ninu nítorí Sara, aya Abrahamu. +Abrahamu sọ fún àwọn ará Gerari pé arabinrin òun ni Sara aya rẹ̀, Abimeleki, ọba Gerari bá ranṣẹ lọ mú Sara. +Ṣugbọn Ọlọrun tọ Abimeleki wá lóru lójú àlá, ó sì wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀! Ikú ti pa ọ́ tán báyìí, nítorí pé obinrin tí o mú sọ́dọ̀, aya aláya ni.” +Ṣugbọn Abimeleki kò tíì bá Sara lòpọ̀ rárá, ó bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, o wá lè pa àwọn eniyan aláìṣẹ̀ bí? +Ṣebí ẹnu ara rẹ̀ ni ó fi sọ pé arabinrin òun ni, tí obinrin náà sì sọ pé arakunrin òun ni. Ohun tí mo ṣe tí ó di ẹ̀ṣẹ̀ yìí, òtítọ́ inú ati àìmọ̀ ni mo fi ṣe é.” +Ọlọrun dá a lóhùn lójú àlá, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé òtítọ́ inú ni o fi ṣe ohun tí o ṣe, èmi ni mo sì pa ọ́ mọ́ tí n kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ mí, ìdí sì nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án. +Ǹjẹ́ nisinsinyii, dá obinrin náà pada fún ọkọ rẹ̀, nítorí pé wolii ni ọkunrin náà yóo gbadura fún ọ, o óo sì yè. Ṣugbọn bí o kò bá dá a pada, mọ̀ dájú pé o óo kú, àtìwọ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ.” +Abimeleki yára dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó pe gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ jọ, ó ro gbogbo nǹkan wọnyi fún wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. +Abimeleki bá pe Abrahamu, ó bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe wá báyìí? Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́ tí o fi ti ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí sí èmi ati ìjọba mi lọ́rùn? Ohun tí o ṣe sí mi yìí kò dára rárá!” +Abrahamu ati Abimeleki. +OLUWA bẹ Sara wò gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, ó sì ṣe fún un gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. +Sara bá pe Abrahamu, ó sọ fún un pé, “Lé ẹrubinrin yìí jáde pẹlu ọmọ rẹ̀, nítorí pé ọmọ ẹrubinrin yìí kò ní jẹ́ àrólé pẹlu Isaaki ọmọ mi.” +Ọ̀rọ̀ yìí kò dùn mọ́ Abrahamu ninu nítorí Iṣimaeli, ọmọ rẹ̀. +Ṣugbọn Ọlọrun wí fún Abrahamu pé, “Má ṣe jẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ ọmọ yìí ati ti ẹrubinrin rẹ, ohunkohun tí Sara bá wí fún ọ ni kí o ṣe, nítorí pé orúkọ Isaaki ni wọn yóo fi máa pe atọmọdọmọ rẹ. +N óo sọ ọmọ ẹrubinrin náà di orílẹ̀ èdè ńlá pẹlu, nítorí ọmọ rẹ ni òun náà.” +Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó mú oúnjẹ ati omi sinu ìgò aláwọ kan, ó dì wọ́n fún Hagari, ó kó wọn kọ́ ọ léjìká, ó fa ọmọ rẹ̀ lé e lọ́wọ́, ó ní kí wọn ó jáde kúrò nílé. Hagari jáde nílé, ó bá ń rìn káàkiri ninu aginjù Beeriṣeba. +Nígbà tí omi tán ninu ìgò aláwọ náà, Hagari fi ọmọ náà sílẹ̀ lábẹ́ igbó ṣúúrú kan tí ó wà níbẹ̀. +Ó lọ jókòó ní òkèèrè, ó takété sí i, ó tó ìwọ̀n ibi tí ọfà tí eniyan bá ta lè balẹ̀ sí, nítorí ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “Má jẹ́ kí n wo àtikú ọmọ mi.” +Bí ó ṣe jókòó tí ó takété sí ọmọ náà, ọmọ fi igbe ta, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Ọlọrun gbọ́ igbe ọmọ náà, angẹli Ọlọrun bá ké sí Hagari láti ọ̀run wá, ó bi í pé, “Kí ni ó ń dààmú ọkàn rẹ, Hagari? Má bẹ̀rù, nítorí Ọlọrun ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí ó wà. +Dìde, lọ gbé e, kí o sì rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, nítorí n óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.” +Ọlọrun bá la Hagari lójú, ó rí kànga kan, ó rọ omi kún inú ìgò aláwọ rẹ̀, ó sì fún ọmọdekunrin náà mu. +Sara lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún Abrahamu lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, ní àkókò tí Ọlọrun sọ fún un. +Ọlọrun wà pẹlu ọmọ náà, ó dàgbà, ó ń gbé ninu aginjù, ó sì mọ ọfà ta tóbẹ́ẹ̀ tí ó di atamátàsé. +Ó ń gbé inú aginjù Parani, ìyá rẹ̀ sì fẹ́ aya fún un ní ilẹ̀ Ijipti. +Ní àkókò náà, Abimeleki ati Fikoli, olórí ogun rẹ̀, sọ fún Abrahamu pé, “Ọlọrun wà pẹlu rẹ ninu ohun gbogbo tí ò ń ṣe. +Nítorí náà, fi Ọlọrun búra fún mi níhìn-ín yìí, pé o kò ní hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi, tabi sí àwọn ọmọ mi, tabi sí ìran mi, ṣugbọn bí mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ náà yóo jẹ́ olóòótọ́ sí mi ati sí ilẹ̀ tí o ti ń ṣe àtìpó.” +Abrahamu bá sọ pé òun yóo búra. +Abrahamu rò fún Abimeleki bí àwọn iranṣẹ Abimeleki ti fi ipá gba kànga omi kan lọ́wọ́ rẹ̀, +Abimeleki bá dá a lóhùn, ó ní “N kò mọ ẹni tí ó ṣe bẹ́ẹ̀, o kò sọ fún mi, n kò gbọ́ nǹkankan nípa rẹ̀, àfi bí o ti ń sọ yìí.” +Abrahamu fún Abimeleki ní aguntan ati mààlúù, àwọn mejeeji bá jọ dá majẹmu. +Abrahamu ya abo ọmọ aguntan meje ninu agbo rẹ̀ sọ́tọ̀. +Abimeleki bá bi Abrahamu, ó ní, “Kí ni ìtumọ̀ abo ọmọ aguntan meje tí o yà sọ́tọ̀ wọnyi?” +Abrahamu sọ ọmọkunrin náà ní Isaaki. +Abrahamu dá a lóhùn pé, “Gba abo ọmọ aguntan meje wọnyi lọ́wọ́ mi, kí o lè jẹ́ ẹlẹ́rìí mi pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.” +Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Beeriṣeba, nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn mejeeji ti búra. +Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe dá majẹmu ní Beeriṣeba. Abimeleki ati Fikoli, olórí ogun rẹ̀, sì pada lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Filistia. +Abrahamu gbin igi tamarisiki kan sí Beeriṣeba, ó sì ń sin OLUWA Ọlọrun ayérayé níbẹ̀. +Abrahamu gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ìgbà pípẹ́. +Ó kọlà abẹ́ fún ọmọ náà nígbà tí ó di ọmọ ọjọ́ kẹjọ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un. +Abrahamu jẹ́ ẹni ọgọrun-un (100) ọdún nígbà tí a bí Isaaki fún un. +Sara wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ni yóo sì rẹ́rìn-ín.” +Ó tún wí pé, “Ta ni ó lè sọ fún Abrahamu pé Sara yóo fún ọmọ lọ́mú? Sibẹsibẹ mo bí ọmọ fún un nígbà tí ó ti di arúgbó.” +Ọmọ náà dàgbà, ó sì já lẹ́nu ọmú, Abrahamu sì se àsè ńlá ní ọjọ́ tí ọmọ náà já lẹ́nu ọmú. +Ní ọjọ́ kan, Sara rí ọmọ tí Hagari, ará Ijipti bí fún Abrahamu, níbi tí ó ti ń bá Isaaki, ọmọ rẹ̀, ṣeré. +A Bí Isaaki. +Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, Ọlọrun dán Abrahamu wò, ó ní, “Abrahamu!” Abrahamu dáhùn pé, “Èmi nìyí.” +Abrahamu nawọ́ mú ọ̀bẹ láti pa ọmọ rẹ̀. +Ṣugbọn angẹli OLUWA pè é láti òkè ọ̀run, ó ní, “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.” +Angẹli náà wí fún un pé, “Má ṣe pa ọmọ náà rárá, má sì ṣe é ní ohunkohun, nítorí pé nisinsinyii mo mọ̀ dájú pé o bẹ̀rù Ọlọrun, nígbà tí o kò kọ̀ láti fi ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o bí rúbọ sí èmi Ọlọrun.” +Bí Abrahamu ti gbé orí sókè, tí ó wo ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí àgbò kan tí ó fi ìwo kọ́ pàǹtí. Ó lọ mú àgbò náà, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. +Nítorí náà ni Abrahamu ṣe sọ ibẹ̀ ní “OLUWA yóo pèsè,” bí wọ́n ti ń wí títí di òní, pé, “Ní orí òkè OLUWA ni yóo ti pèsè.” +Angẹli OLUWA tún pe Abrahamu láti òkè ọ̀run ní ìgbà keji, +ó ní, “Mo fi ara mi búra pé nítorí ohun tí o ṣe yìí, tí o kò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ kan ṣoṣo, +n óo bukun ọ lọpọlọpọ, n óo sọ àwọn ọmọ ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi yanrìn etí òkun. Àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóo máa ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo ìgbà. +Nípasẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ni n óo ti bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, nítorí pé o gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.” +Abrahamu bá pada tọ àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ lọ, wọ́n bá jọ gbéra, wọ́n pada lọ sí Beeriṣeba, Abrahamu sì ń gbé ibẹ̀. +Ọlọrun ní, “Mú Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o fẹ́ràn, kí o lọ sí ilẹ̀ Moraya, kí o sì fi ọmọ náà rú ẹbọ sísun lórí ọ̀kan ninu àwọn òkè tí n óo júwe fún ọ.” +Lẹ́yìn náà, wọ́n wá sọ fún Abrahamu pé Milika ti bímọ fún Nahori arakunrin rẹ̀. +Usi ni àkọ́bí, Busi ni wọ́n bí tẹ̀lé e, lẹ́yìn náà Kemueli tíí ṣe baba Aramu. +Lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Kesedi, Haso, Pilidaṣi, Jidilafi ati Betueli. +Betueli ni baba Rebeka. Àwọn mẹjẹẹjọ yìí ni Milika bí fún Nahori, arakunrin Abrahamu. +Nahori tún ní obinrin mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Reuma, òun ni ó bí Teba, Gahamu, Tahaṣi, ati Mahaka fún Nahori. +Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó mú meji ninu àwọn ọdọmọkunrin ilé rẹ̀, ati Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Ó gé igi fún ẹbọ sísun, lẹ́yìn náà wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí ibi tí Ọlọrun ti júwe fún Abrahamu. +Ní ọjọ́ kẹta, bí Abrahamu ti wo ọ̀kánkán, ó rí ibi tí Ọlọrun júwe fún un ní òkèèrè. +Abrahamu bá sọ fún àwọn ọdọmọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé e, ó ní, “Ẹ dúró ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ níhìn-ín, èmi ati ọmọ yìí yóo rìn siwaju díẹ̀, láti lọ sin Ọlọ́run, a óo sì pada wá bá yín.” +Abrahamu gbé igi ẹbọ sísun náà lé Isaaki, ọmọ rẹ̀ lórí, ó mú ọ̀bẹ ati iná lọ́wọ́. Àwọn mejeeji jọ ń lọ. +Isaaki bá pe Abrahamu, baba rẹ̀, ó ní, “Baba mi.” Baba rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ni, ọmọ mi?” Isaaki ní, “Wò ó, a rí iná ati igi, àgbò tí a óo fi rú ẹbọ sísun dà?” +Abrahamu dá a lóhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni yóo pèsè, àgbò tí a óo fi rú ẹbọ sísun náà.” Àwọn mejeeji tún ń bá ìrìn àjò wọn lọ. +Nígbà tí wọ́n dé ibi tí Ọlọrun júwe fún Abrahamu, ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó to igi sórí pẹpẹ náà, ó di Isaaki ọmọ rẹ̀ tọwọ́ tẹsẹ̀, ó bá gbé e ka orí igi lórí pẹpẹ tí ó tẹ́. +Ọlọrun Pàṣẹ fún Abrahamu pé Kí Ó fi Isaaki Rúbọ. +Ọdún mẹtadinlaadoje (127) ni Sara gbé láyé. +Efuroni alára wà ní ìjókòó pẹlu àwọn ará Hiti yòókù, lójú gbogbo àwọn ará ìlú náà ni ó ti dá Abrahamu lóhùn, ó ní, +“Rárá o! oluwa mi, gbọ́, mo fún ọ ní ilẹ̀ náà, ati ihò tí ó wà ninu rẹ̀, lójú gbogbo àwọn eniyan mi ni mo sì ti fún ọ, lọ sin aya rẹ sibẹ.” +Nígbà náà ni Abrahamu tẹríba níwájú gbogbo wọn. +Ó bá sọ fún Efuroni lójú gbogbo wọn, ó ní, “Ṣugbọn, bí ó bá ti ọkàn rẹ wá, fún mi ní ilẹ̀ náà, kí n sì san owó rẹ̀ fún ọ. Gbà á lọ́wọ́ mi, kí n lè lọ sin aya mi sibẹ.” +Efuroni dá Abrahamu lóhùn, ó ní, +“Olúwa mi, gbọ́, ilẹ̀ yìí kò ju irinwo (400) ìwọ̀n ṣekeli fadaka lọ, èyí kò tó nǹkankan láàrin èmi pẹlu rẹ. Lọ sin òkú aya rẹ.” +Abrahamu gbà bí Efuroni ti wí, ó bá wọn irinwo (400) ìwọ̀n ṣekeli fadaka tí Efuroni dárúkọ fún un lójú gbogbo wọn, ó lo ìwọ̀n tí àwọn oníṣòwò ìgbà náà ń lò. +Bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ Efuroni ní Makipela, tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn Mamure ṣe di ti Abrahamu, ati ihò tí ó wà ninu ilẹ̀ náà, ati gbogbo igi tí ó wà ninu rẹ̀ jákèjádò. +Gbogbo àwọn ará Hiti tí wọ́n wà níbẹ̀ jẹ́rìí sí i pé ilẹ̀ náà di ti Abrahamu. +Lẹ́yìn náà, Abrahamu lọ sin òkú Sara sinu ihò ilẹ̀ Makipela, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Mamure, ní agbègbè Heburoni ní ilẹ̀ Kenaani. +Ó kú ní Kiriati Ariba, ní Heburoni, ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu sọkún, ó sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. +Ilẹ̀ náà ati ihò tí ó wà ninu rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu láti máa lò bí itẹ́ òkú. +Nígbà tí ó yá, Abrahamu dìde níwájú òkú Sara, ó lọ bá àwọn ará Hiti, ó ní, +“Àlejò ni mo jẹ́ láàrin yín, ẹ bá mi wá ilẹ̀ ní ìwọ̀nba ninu ilẹ̀ yín tí mo lè máa lò bí itẹ́ òkú, kí n lè sin òkú aya mi yìí, kí ó kúrò nílẹ̀.” +Àwọn ará Hiti dá Abrahamu lóhùn, wọ́n ní, +“Gbọ́, oluwa wa, olóyè pataki ni o jẹ́ láàrin wa. Sin òkú aya rẹ síbikíbi tí ó bá wù ọ́ jùlọ ninu àwọn itẹ́ òkú wa, kò sí ẹnikẹ́ni ninu wa tí kò ní fún ọ ní itẹ́ òkú rẹ̀, tabi tí yóo dí ọ lọ́wọ́, pé kí o má ṣe ohun tí o fẹ́ ṣe.” +Abrahamu bá dìde, ó tẹríba níwájú wọn, +ó ní, “Bí ẹ bá fẹ́ kí n sin òkú aya mi kúrò nílẹ̀ nítòótọ́, ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì bá mi sọ fún Efuroni ọmọ Sohari, +kí ó fún mi ní ihò Makipela, òun ni ó ni ihò náà, ní ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ̀ ni ó wà. Títà ni mo fẹ́ kí ó tà á fún mi ní iyekíye tí ilẹ̀ náà bá tó, lójú gbogbo yín, n óo sì lè máa lo ilẹ̀ náà bí itẹ́ òkú.” +Abrahamu ti darúgbó, Ọlọrun sì ti bukun un ní gbogbo ọ̀nà. +Iranṣẹ náà mú mẹ́wàá ninu àwọn ràkúnmí oluwa rẹ̀, ó gba oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn àtàtà lọ́wọ́ oluwa rẹ̀, ó jáde lọ sí ilẹ̀ Mesopotamia, sí ìlú Nahori. +Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ní déédé ìgbà tí àwọn obinrin máa ń jáde lọ pọn omi, ó mú kí àwọn ràkúnmí rẹ̀ kúnlẹ̀ lẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá kànga kan, +ó sì gbadura báyìí pé “Ìwọ OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, jọ̀wọ́, ṣe ọ̀nà mi ní rere lónìí, kí o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí Abrahamu, oluwa mi. +Bí mo ti dúró lẹ́bàá kànga yìí, tí àwọn ọdọmọbinrin ìlú yìí sì ń jáde wá láti pọn omi, +jẹ́ kí ọmọbinrin tí mo bá sọ fún pé jọ̀wọ́ sọ ìkòkò omi rẹ kalẹ̀ kí o fún mi ní omi mu, tí ó sì dá mi lóhùn pé, ‘Omi nìyí, mu, n óo sì fún àwọn ràkúnmí rẹ mu pẹlu,’ jẹ́ kí olúwarẹ̀ jẹ́ ẹni náà tí o yàn fún Isaaki, iranṣẹ rẹ. Èyí ni n óo fi mọ̀ pé o ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí oluwa mi.” +Kí ó tó dákẹ́ adura rẹ̀ ni Rebeka ọmọ Betueli yọ sí i pẹlu ìkòkò omi ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Nahori ni Betueli jẹ́, tí Milika bí fún un. Nahori yìí jẹ́ arakunrin Abrahamu. +Arẹwà wundia ni Rebeka, kò sì tíì mọ ọkunrin. Bí ó ti dé, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sinu odò, ó pọn omi rẹ̀, ó sì jáde. +Iranṣẹ Abrahamu bá sáré tẹ̀lé e, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní omi díẹ̀ mu ninu ìkòkò rẹ.” +Ọmọbinrin náà dáhùn pé, “Omi nìyí, oluwa mi.” Ó sì yára gbé ìkòkò rẹ̀ lé ọwọ́ rẹ̀ láti fún un ní omi mu. +Bí Rebeka ti fún un ní omi tán, ó ní, “Jẹ́ kí n pọn omi fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu, títí tí gbogbo wọn yóo fi mu omi tán” +Abrahamu sọ fún iranṣẹ rẹ̀ tí ó dàgbà jù ninu ilé rẹ̀, ẹni tí í ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó ní, pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abẹ́ itan mi, +Kíá, ó ti da omi tí ó kù ninu ìkòkò rẹ̀ sinu agbada tí ẹran fi ń mu omi, ó sáré pada lọ pọn sí i, títí tí gbogbo wọn fi mu omi káríkárí. +Ọkunrin náà fọwọ́ lẹ́rán, ó ń wò pé bóyá lóòótọ́ ni OLUWA ti ṣe ọ̀nà òun ní rere ni tabi bẹ́ẹ̀ kọ́. +Nígbà tí àwọn ràkúnmí rẹ̀ mu omi tán, tí gbogbo wọn yó, ọkunrin yìí fún un ní òrùka imú tí a fi wúrà ṣe, tí ó wọ̀n tó ìwọ̀n ìdajì ṣekeli, ati ẹ̀gbà ọwọ́ meji tí a fi wúrà ṣe tí ó wọ̀n tó ìwọ̀n ṣekeli wúrà mẹ́wàá. +Lẹ́yìn náà, ó bi í pé, “Jọ̀wọ́, kí ni orúkọ baba rẹ? Ǹjẹ́ ààyè ṣì wà ní ilé yín tí a lè wọ̀ sí ní alẹ́ yìí?” +Ó dá a lóhùn, ó ní, “Betueli, ọmọ tí Milika bí fún Nahori ni baba mi.” +Ó tún fi kún un pé, “A ní ọpọlọpọ koríko ati oúnjẹ ẹran, ààyè sì wà láti sùn ní ilé wa.” +Ọkunrin náà bá tẹríba, ó sì sin OLUWA, +ó sọ pé, “Ọpẹ́ ni fún ọ OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, tí kò gbàgbé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati òdodo rẹ̀ sí oluwa mi. Ní tèmi, OLUWA ti tọ́ mi sọ́nà tààrà, sí ilé àwọn ìbátan oluwa mi.” +Ọmọbinrin náà bá sáré lọ sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀. +Rebeka ní arakunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Labani. Labani yìí ni ó sáré lọ bá ọkunrin náà ní ìdí kànga. +n óo sì mú kí o búra ní orúkọ OLUWA Ọlọrun ọ̀run ati ayé, pé o kò ní fẹ́ aya fún ọmọ mi lára àwọn ọmọbinrin ará Kenaani tí mò ń gbé, +Lẹ́yìn tí ó rí òrùka ati ẹ̀gbà ọwọ́ lọ́wọ́ arabinrin rẹ̀, tí ó sì ti gbọ́ ohun tí Rebeka sọ pé ọkunrin náà sọ fún òun, ó lọ bá ọkunrin náà níbi tí ó dúró sí lẹ́bàá kànga pẹlu àwọn ràkúnmí rẹ̀. +Labani sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ilé, ìwọ ẹni tí OLUWA bukun. Èéṣe tí o fi dúró níta gbangba? Mo ti tọ́jú ilé, mo sì ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún àwọn ràkúnmí rẹ.” +Ọkunrin náà bá wọlé, Labani sì tú gàárì àwọn ràkúnmí rẹ̀, ó fi koríko ati oúnjẹ fún wọn. Ó fún un ní omi láti fi ṣan ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ẹsẹ̀ àwọn ọkunrin tí wọ́n bá a wá. +Wọ́n gbé oúnjẹ wá fún un pé kí ó jẹ, ṣugbọn ó wí pé, “N kò ní jẹun títí n óo fi jíṣẹ́ tí wọ́n rán mi.” Labani dáhùn, ó ní, “À ń gbọ́.” +Ọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Iranṣẹ Abrahamu ni mí, +OLUWA ti bukun oluwa mi lọpọlọpọ, ó sì ti di eniyan ńlá. OLUWA ti fún un ní ọpọlọpọ mààlúù ati agbo ẹran, ọpọlọpọ fadaka ati wúrà, ọpọlọpọ iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ati ọpọlọpọ ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. +Sara, aya oluwa mi bí ọmọkunrin kan fún un lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, ọmọ yìí sì ni oluwa mi fi ohun gbogbo tí ó ní fún. +Oluwa mi mú mi búra pé n kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ òun láàrin àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí òun ń gbé. +Ó ni mo gbọdọ̀ wá síhìn-ín, ní ilé baba òun ati sọ́dọ̀ àwọn ẹbí òun láti fẹ́ aya fún ọmọ òun. +Mo sì bi oluwa mi nígbà náà pé, ‘bí obinrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá ńkọ́?’ +ṣugbọn o óo lọ sí ìlú mi, lọ́dọ̀ àwọn ẹbí mi, láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.” +Ṣugbọn ó sọ fún mi pé, ‘OLUWA náà tí òun ń fi gbogbo ayé òun sìn yóo rán angẹli rẹ̀ sí mi, yóo sì ṣe ọ̀nà mi ní rere. Ó ní, mo ṣá gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ òun láàrin àwọn eniyan òun ati ní ilé baba òun. +Nígbà náà ni ọrùn mi yóo tó mọ́ kúrò ninu ìbúra tí mo bú fún òun. Bí mo bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan òun, tí wọ́n bá kọ̀, tí wọn kò jẹ́ kí ọmọbinrin wọn bá mi wá, ọrùn mi yóo mọ́ kúrò ninu ìbúra tí mo bú.’ +“Lónìí, bí mo ti dé ìdí kànga tí ó wà lẹ́yìn ìlú, bẹ́ẹ̀ ni mo gbadura sí Ọlọrun, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, bí ó bá jẹ́ pé o ti ṣe ọ̀nà mi ní rere nítòótọ́, +bí mo ti dúró nídìí kànga yìí, ọmọbinrin tí ó bá wá pọnmi, tí mo bá sì sọ fún pé, jọ̀wọ́, fún mi lómi mu ninu ìkòkò omi rẹ, +tí ó bá wí fún mi pé, “Omi nìyí, mu, n óo sì pọn fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu”, nígbà náà ni n óo mọ̀ pé òun ni obinrin náà tí ìwọ OLUWA ti yàn láti jẹ́ aya ọmọ oluwa mi.’ +Kí n tó dákẹ́ adura mi, Rebeka yọ pẹlu ìkòkò omi ní èjìká rẹ̀. Ó sọ̀kalẹ̀ lọ sinu odò, ó sì pọnmi. Mo bá wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ fún mi lómi mu.’ +Kíá ni ó sọ ìkòkò omi rẹ̀ kúrò ní èjìká, tí ó sì wí pé, ‘Omi nìyí, mu, n óo pọn fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu.’ Mo bá mu omi, ó sì fún àwọn ràkúnmí mi lómi mu pẹlu. +Nígbà náà ni mo bi í ọmọ ẹni tí í ṣe. Ó dá mi lóhùn pé, Betueli ọmọ Nahori, tí Milika bí fún un ni baba òun. Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo fi òrùka sí imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà ọwọ́ bọ̀ ọ́ lọ́wọ́. +Nígbà náà ni mo tẹríba, mo sì sin OLUWA, mo yin OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi lógo, ẹni tí ó tọ́ mi sí ọ̀nà tààrà láti wá fẹ́ ọmọ ẹbí oluwa mi fún ọmọ rẹ̀. +Nítorí náà, ẹ sọ fún mi bí ẹ óo bá ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu oluwa mi tabi ẹ kò ní ṣe ẹ̀tọ́, kí n lè mọ̀ bí n óo ṣe rìn.” +Iranṣẹ náà dá a lóhùn pé, “Bí ọmọbinrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí, ṣé kí n mú ọmọ rẹ pada sí ilẹ̀ tí o ti wá síhìn-ín?” +Labani ati Betueli dáhùn pé, “Ati ọ̀dọ̀ OLUWA ni nǹkan yìí ti wá, àwa kò sì ní sọ pé bẹ́ẹ̀ ni tabi bẹ́ẹ̀ kọ́. +Rebeka alára nìyí níwájú rẹ yìí, máa mú un lọ kí ó sì di aya ọmọ oluwa rẹ, bí OLUWA ti wí.” +Nígbà tí iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó wólẹ̀ ó sì dojúbolẹ̀ níwájú OLUWA. +Ó sì mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye tí a fi fadaka ati wúrà ṣe jáde, ati àwọn aṣọ àtàtà, ó kó wọn fún Rebeka. Ó sì kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye fún arakunrin rẹ̀ ati ìyá rẹ̀ pẹlu. +Nígbà náà ni òun ati àwọn tí wọ́n bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, wọ́n sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iranṣẹ Abrahamu wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n lọ jíṣẹ́ fún oluwa mi.” +Ẹ̀gbọ́n ati ìyá Rebeka dáhùn pé, “Jẹ́ kí omidan náà ṣe bí ọjọ́ mélòó kan sí i lọ́dọ̀ wa, bí kò tilẹ̀ ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ, kí ó tó máa bá yín lọ!” +Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má wulẹ̀ dá mi dúró mọ́, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ṣe ọ̀nà mi ní rere, ẹ jẹ́ kí n lọ bá oluwa mi.” +Wọ́n dáhùn pé, “��� jẹ́ kí á kúkú pe omidan náà kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” +Wọ́n bá pe Rebeka, wọ́n bi í pé, “Ṣé o óo máa bá ọkunrin yìí lọ?” Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, n óo lọ.” +Wọ́n bá gbà pé kí Rebeka arabinrin wọn máa lọ, pẹlu olùtọ́jú rẹ̀ láti ìgbà èwe rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, pẹlu àwọn ọkunrin tí wọ́n bá a wá. +Abrahamu dáhùn pé, “Rárá o! O kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi pada sibẹ. +Wọ́n súre fún Rebeka, wọ́n wí pé, “Arabinrin wa, o óo bírún, o óo bígba. Àwọn ọmọ rẹ yóo máa borí àwọn ọ̀tá wọn.” +Rebeka ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ bá gun ràkúnmí, wọ́n tẹ̀lé ọkunrin náà. Bẹ́ẹ̀ ni iranṣẹ náà ṣe mú Rebeka lọ. +Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, Isaaki ti wá láti Beeri-lahai-roi, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nẹgẹbu. +Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó lọ ṣe àṣàrò ninu pápá, ojú tí ó gbé sókè, ó rí i tí àwọn ràkúnmí ń bọ̀. +Ojú tí Rebeka náà gbé sókè, ó rí Isaaki, ó sọ̀kalẹ̀ lórí ràkúnmí. +Ó bi iranṣẹ Abrahamu náà pé, “Ta ni ó ń rìn ninu pápá lọ́ọ̀ọ́kán tí ó ń bọ̀ wá pàdé wa yìí?” Iranṣẹ náà dá a lóhùn pé, “Olúwa mi ni.” Rebeka bá mú ìbòjú rẹ̀, ó dà á bojú. +Nígbà tí wọ́n pàdé Isaaki, iranṣẹ náà ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un. +Isaaki bá mú Rebeka wọ inú àgọ́ Sara ìyá rẹ̀, Rebeka sì di aya rẹ̀, Isaaki sì fẹ́ràn rẹ̀. Nígbà yìí ni Isaaki kò tó ṣọ̀fọ̀ ìyá rẹ̀ mọ́. +OLUWA Ọlọrun ọ̀run, tí ó mú mi jáde láti ilé baba mi, ati ilẹ̀ tí wọ́n bí mi sí, tí ó bá mi sọ̀rọ̀, tí ó sì búra fún mi pé, àwọn ọmọ mi ni òun yóo fi ilẹ̀ yìí fún, yóo rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, o óo sì fẹ́ aya wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀. +Ṣugbọn bí obinrin náà bá kọ̀ tí kò tẹ̀lé ọ, nígbà náà ọrùn rẹ yóo mọ́ ninu ìbúra tí o búra fún mi, ṣá má ti mú ọmọ mi pada sibẹ.” +Iranṣẹ náà bá ti ọwọ́ rẹ̀ bọ abẹ́ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, ó sì búra láti ṣe ohun tí Abrahamu pa láṣẹ fún un. +Wọ́n Gbeyawo fún Isaaki. +Abrahamu fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ketura. +Ilẹ̀ tí Abrahamu rà lọ́wọ́ àwọn ará Hiti ni wọ́n sin ín sí pẹlu Sara aya rẹ̀, +Lẹ́yìn ikú Abrahamu, Ọlọrun bukun Isaaki ọmọ rẹ̀. Isaaki sì ń gbé Beeri-lahai-roi. +Ìran Iṣimaeli, ọmọ Abrahamu, tí Hagari, ará Ijipti, ọmọ-ọ̀dọ̀ Sara bí fún un nìyí: +Àwọn ọmọkunrin Iṣimaeli nìwọ̀nyí bí a ti bí wọn tẹ̀lé ara wọn: Nebaiotu, Kedari, Adibeeli, +Mibisamu, Miṣima, Duma, Masa, +Hadadi, Tema, Jeturi, Nafiṣi ati Kedema. +Àwọn ni ọmọkunrin Iṣimaeli. Wọ́n jẹ́ ọba ẹ̀yà mejila, orúkọ wọn ni wọ́n sì fi ń pe àwọn ìletò ati àgọ́ wọn. +Iye ọdún tí Iṣimaeli gbé láyé jẹ́ ọdún mẹtadinlogoje (137). Nígbà tí ó kú a sin ín pẹlu àwọn eniyan rẹ̀. +Àwọn ọmọ Iṣimaeli sì ń gbé ilẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Hafila títí dé Ṣuri, tí ó wà ní òdìkejì Ijipti, ní apá Asiria. Wọ́n tẹ̀dó sí òdìkejì àwọn eniyan wọn. +Ìran Isaaki ọmọ Abrahamu nìyí, Abrahamu ni baba Isaaki. +Ketura bí Simirani, Jokiṣani, Medani, Midiani, Iṣibaku ati Ṣua fún un. +Nígbà tí Isaaki di ẹni ogoji ọdún, ó fẹ́ Rebeka. Rebeka jẹ́ ọmọ Betueli, ará Aramea, tí ń gbé Padani-aramu, ó sì tún jẹ́ arabinrin Labani, ara Aramea. +Isaaki gbadura sí OLUWA fún aya rẹ̀ tí ó yàgàn, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, Rebeka aya rẹ̀ sì lóyún. +Àwọn ọmọ ń ti ara wọn síhìn-ín sọ́hùn-ún ninu rẹ̀, ó sì wí pé, “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni yóo máa rí, kí ni mo kúkú wà láàyè fún?” Ó bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà wò lọ́dọ̀ OLUWA. +OLUWA wí fún un pé, “Orílẹ̀-èdè meji ni ó wà ninu rẹ,a óo sì pín àwọn oríṣìí eniyan meji tí o óo bí níyà,ọ̀kan yóo lágbára ju ekeji lọ,èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo sì máa sin àbúrò.” +Nígbà tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ pé, ìbejì ni ó bí nítòótọ́. +Èyí àkọ́bí pupa, gbogbo ara rẹ̀ dàbí aṣọ onírun. Nítorí náà ni wọ́n fi sọ ọ́ ní Esau. +Nígbà tí wọ́n bí èyí ekeji, rírọ̀ ni ó fi ọwọ́ kan rọ̀ mọ́ èyí àkọ́bí ní gìgísẹ̀. Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní Jakọbu. Ẹni ọgọta ọdún ni Isaaki nígbà tí Rebeka bí wọn. +Nígbà tí àwọn ọmọ náà dàgbà, Esau di ògbójú ọdẹ, a sì máa lọ sí oko ọdẹ nígbà gbogbo, ṣugbọn Jakọbu jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ilé ni ó sì máa ń sábà gbé ní tirẹ̀. +Isaaki fẹ́ràn Esau nítorí ẹran ìgbẹ́ tí ó máa ń fún un jẹ nígbà gbogbo, ṣugbọn Jakọbu ni Rebeka fẹ́ràn. +Ní ọjọ́ kan, bí Jakọbu ti ń se ẹ̀bẹ lọ́wọ́ ni Esau ti oko ọdẹ dé, ebi sì ti fẹ́rẹ̀ pa á kú. +Jokiṣani ni baba Ṣeba ati Dedani. Àwọn ọmọ Dedani ni Aṣurimu, Letuṣimu ati Leumimu. +Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jọ̀wọ́ fún mi jẹ ninu ẹ̀bẹ tí ó pupa yìí nítorí pé ebi ń pa mí kú lọ.” (Nítorí ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n ṣe ń pè é ní Edomu.) +Jakọbu bá dáhùn pé, “Kọ́kọ́ gbé ipò àgbà rẹ fún mi ná.” +Esau dá a lóhùn, ó ní, “Ebi ń pa mí kú lọ báyìí, ò ń sọ̀rọ̀ ipò àgbà, kí ni ipò àgbà fẹ́ dà fún mi?” +Jakọbu dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi ná.” Esau bá búra fún Jakọbu, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gbé ipò àgbà fún un. +Jakọbu bá fún Esau ní àkàrà ati ẹ̀bẹ ati ẹ̀fọ́. Nígbà tí Esau jẹ, tí ó mu tán, ó bá tirẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Esau ṣe fi ojú tẹmbẹlu ipò àgbà rẹ̀. +Àwọn ọmọ Midiani ni Efai, Eferi, Hanoku, Abida ati Elidaa. Àwọn ni àwọn ìran tó ṣẹ̀ lọ́dọ̀ Ketura. +Ṣugbọn Isaaki ni Abrahamu kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ fún. +Ẹ̀bùn ni ó fún gbogbo ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn bí fún un, kí ó tó kú ni ó sì ti ní kí wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ Isaaki, kí wọ́n lọ máa gbé ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ náà. +Ọdún tí Abrahamu gbé láyé jẹ́ aadọsan-an ọdún ó lé marun-un (175), +ó di arúgbó kùjọ́kùjọ́, kí ó tó kú. +Àwọn ọmọ rẹ̀, Isaaki ati Iṣimaeli, sin òkú rẹ̀ sinu ihò òkúta Makipela, ninu pápá Efuroni, ọmọ Sohari, ará Hiti, níwájú Mamure. +Àwọn Ọmọ Mìíràn Tí Abrahamu Bí. +Ní àkókò kan, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ sí ìyàn tí ó mú ní ìgbà Abrahamu. Isaaki bá tọ Abimeleki ọba àwọn ará Filistini lọ ní Gerari. +Abimeleki bá dá a lóhùn pé, “Irú kí ni o dánwò sí wa yìí? Ǹjẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọnyi bá ti bá aya rẹ lòpọ̀ ńkọ́? O ò bá mú ẹ̀bi wá sórí wa.” +Nítorí náà Abimeleki kìlọ̀ fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan ọkunrin yìí tabi aya rẹ̀, pípa ni wọn yóo pa á.” +Isaaki dá oko ní ilẹ̀ náà, láàrin ọdún kan ṣoṣo ó rí ìkórè ìlọ́po lọ́nà ọgọrun-un (100) ohun tí ó gbìn nítorí OLUWA bukun un. +Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní àníkún títí ó fi di ọlọ́rọ̀. +Ó ní ọpọlọpọ agbo aguntan ati agbo mààlúù, pẹlu ọpọlọpọ iranṣẹ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Filistia bẹ̀rẹ̀ sí jowú rẹ̀. +Gbogbo kànga tí àwọn iranṣẹ Abrahamu baba rẹ̀ gbẹ́ ní àkókò tí Abrahamu wà láyé ni àwọn ará Filistia rọ́ yẹ̀ẹ̀pẹ̀ dí. +Abimeleki bá wí fún Isaaki pé, “Kúrò lọ́dọ̀ wa, nítorí pé o ti lágbára jù wá lọ.” +Isaaki kúrò níbẹ̀, ó lọ tẹ̀dó sí àfonífojì Gerari. +Isaaki tún àwọn kànga tí wọ́n ti gbẹ́ nígbà ayé Abrahamu baba rẹ̀ gbẹ́, nítorí pé, kò pẹ́ lẹ́yìn tí Abrahamu kú ni àwọn ará Filistia ti dí wọn. Ó sì sọ àwọn kànga náà ní orúkọ tí baba rẹ̀ sọ wọ́n. +Ṣugbọn nígbà tí àwọn iranṣẹ Isaaki gbẹ́ kànga kan ní àfonífojì náà tí wọ́n sì kan omi, +Kí ó tó lọ sí Gerari, Ọlọrun farahàn án, ó sì kìlọ̀ fún un pé kò gbọdọ̀ lọ sí Ijipti, kí ó máa gbé ilẹ̀ tí òun sọ fún un. +àwọn darandaran ará Gerari bá àwọn tí wọn ń da ẹran Isaaki jà, wọ́n wí pé, “Àwa ni a ni omi kànga yìí.” Nítorí náà ni Isaaki ṣe sọ kànga náà ní Eseki, nítorí pé wọ́n bá a jà nítorí rẹ̀. +Àwọn iranṣẹ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, òun náà tún dìjà, nítorí náà Isaaki sọ ọ́ ní Sitina. +Ó kúrò níbẹ̀, ó lọ gbẹ́ kànga mìíràn, ẹnikẹ́ni kò sì bá a jà sí i, ó bá sọ ọ́ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nisinsinyii Ọlọrun ti pèsè ààyè fún wa, a óo sì pọ̀ sí i ní ilẹ̀ yìí.” +Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Beeriṣeba. +OLUWA sì fara hàn án ní òru ọjọ́ tí ó rin ìrìn àjò náà, ó ní, “Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ, má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo bukun ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ nítorí ti Abrahamu iranṣẹ mi.” +Ó bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sin OLUWA. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì gbẹ́ kànga kan sibẹ. +Abimeleki lọ sọ́dọ̀ Isaaki láti Gerari, òun ati Ahusati, olùdámọ̀ràn rẹ̀, ati Fikoli olórí ogun rẹ̀. +Isaaki bá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ tún ń wá lọ́dọ̀ mi, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ lé mi kúrò lọ́dọ̀ yín?” +Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé OLUWA wà pẹlu rẹ, ni a bá rò pé, ó yẹ kí àdéhùn wà láàrin wa, kí á sì bá ọ dá majẹmu, +pé o kò ní pa wá lára, gẹ́gẹ́ bí àwa náà kò ti ṣe ọ́ níbi, àfi ire, tí a sì sìn ọ́ kúrò lọ́dọ̀ wa ní alaafia.” +Ọlọrun ní, “Máa gbé ilẹ̀ yìí, n óo wà pẹlu rẹ, n óo s�� bukun ọ, nítorí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún ní ilẹ̀ wọnyi, n óo sì mú ìlérí mi fún Abrahamu, baba rẹ ṣẹ. +Isaaki bá se àsè fún wọn, wọ́n jẹ, wọ́n mu. +Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, wọ́n ṣe ìbúra láàrin ara wọn, Isaaki bá sìn wọ́n sọ́nà, wọ́n sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní alaafia. +Ní ọjọ́ náà gan-an ni àwọn iranṣẹ rẹ̀ wá sọ fún un pé àwọn kan omi ninu kànga kan tí àwọn gbẹ́. +Ó sọ kànga náà ní Ṣeba. Ìdí nìyí tí orúkọ ìlú náà fi ń jẹ́ Beeriṣeba títí di òní yìí. +Nígbà tí Esau di ẹni ogoji ọdún, ó fẹ́ Juditi, ọmọ Beeri, ará Hiti ati Basemati, ọmọ Eloni, ará Hiti. +Àwọn obinrin mejeeji yìí han Isaaki ati Rebeka léèmọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ayé sú wọn. +N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ wọnyi. Nípasẹ̀ wọn ni n óo bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, +nítorí pé Abrahamu gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, ó sì pa gbogbo òfin ati ìlànà mi mọ́ patapata.” +Isaaki bá ń gbé Gerari. +Nígbà tí àwọn ará ìlú náà bèèrè bí Rebeka ti jẹ́ sí i, ó sọ fún wọn pé arabinrin òun ni. Ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ fún wọn pé iyawo òun ni, nítorí ó rò pé àwọn ará ìlú náà lè pa òun nítorí pe Rebeka jẹ́ arẹwà obinrin. +Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí Isaaki ti ń gbé ìlú náà fún ìgbà pípẹ́, Abimeleki, ọba àwọn ará ìlú Filistia yọjú lójú fèrèsé ààfin rẹ̀, ó rí i tí Isaaki ati Rebeka ń tage. +Abimeleki bá pe Isaaki, ó wí pé, “Àṣé iyawo rẹ ni Rebeka! Kí ni ìdí tí o fi pè é ní arabinrin rẹ fún wa?” Isaaki bá dáhùn pé, “Mo rò pé wọ́n lè pa mí nítorí rẹ̀ ni.” +Isaaki Gbé ní Gerari. +Nígbà tí Isaaki di arúgbó, tí ojú rẹ̀ sì di bàìbàì tóbẹ́ẹ̀ tí kò le ríran mọ́, ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Ọmọ mi.” Esau sì dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí.” +o óo sì lọ gbé e fún baba yín, kí ó jẹ ẹ́, kí ó baà lè súre fún ọ, kí ó tó kú.” +Ṣugbọn Jakọbu dá Rebeka ìyá rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Onírun lára ni Esau, ẹ̀gbọ́n mi, n kò sì ní irun lára. +Ó ṣeéṣe kí baba mi fi ọwọ́ pa mí lára, yóo wá dàbí ẹni pé mo wá fi ṣe ẹlẹ́yà. Nípa bẹ́ẹ̀ n óo fa ègún sórí ara mi dípò ìre.” +Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ègún náà wá sí orí mi, ọmọ mi, ṣá gba ohun tí mo wí, kí o sì lọ mú àwọn ewúrẹ́ náà wá.” +Jakọbu bá lọ mú wọn wá fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì se irú oúnjẹ aládùn tí baba wọn fẹ́ràn. +Lẹ́yìn náà Rebeka mú aṣọ Esau, àkọ́bí rẹ̀, tí ó dára jùlọ, tí ó wà nílé lọ́dọ̀ rẹ̀, ó wọ̀ ọ́ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀. +Ó mú awọ ewúrẹ́ tí ó pa, ó fi bo ọwọ́ Jakọbu ati ibi tí ó ń dán ní ọrùn rẹ̀, +ó sì gbé oúnjẹ aládùn tí ó sè ati àkàrà tí ó tọ́jú fún Jakọbu ọmọ rẹ̀. +Ni Jakọbu bá tọ baba rẹ̀ lọ, ó pè é, ó ní, “Baba mi,” Baba rẹ̀ bá dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi, ìwọ ta ni?” +Jakọbu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni, mo ti ṣe bí o ti wí, dìde jókòó, kí o sì jẹ ninu ẹran ìgbẹ́ tí mo pa, kí o lè súre fún mi.” +Isaaki wí pé, “Ṣé o rí i báyìí pé mo ti darúgbó, n kò sì mọ ọjọ́ ikú mi. +Ṣugbọn Isaaki bi í léèrè pé, “O ti ṣe é tí o fi rí ẹran pa kíákíá bẹ́ẹ̀ ọmọ mi?” Jakọbu dáhùn pé “OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó ṣe ọ̀nà mi ní rere.” +Isaaki bá wí tìfura-tìfura pé, “Súnmọ́ mi, kí n fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Esau ọmọ mi ni ọ́ lóòótọ́.” +Jakọbu bá súnmọ́ Isaaki baba rẹ̀, baba rẹ̀ fọwọ́ pa á lára, ó wí pé, “Ọwọ́ Esau ni ọwọ́ yìí, ṣugbọn ohùn Jakọbu ni ohùn yìí.” +Kò sì dá Jakọbu mọ̀, nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ ní irun bíi ti Esau ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó bá súre fún un. +Ó bèèrè pé, “Ṣé ìwọ gan-an ni Esau, ọmọ mi?” Jakọbu bá dáhùn pé, “Èmi ni.” +Nígbà náà ni ó wí pé, “Gbé oúnjẹ náà súnmọ́ mi, kí n jẹ ninu ẹran tí ọmọ mi pa, kí n sì súre fún ọ.” Jakọbu bá gbé oúnjẹ náà súnmọ́ ọn, ó jẹ ẹ́, ó bu ọtí waini fún un, ó sì mu ún. +Isaaki baba rẹ̀ bá pè é ó ní, “Súnmọ́ mi, ọmọ mi, kí o sì fi ẹnu kò mí lẹ́nu.” +Jakọbu bá súnmọ́ baba rẹ̀, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Baba rẹ̀ gbóòórùn aṣọ rẹ̀, ó sì súre fún un, ó ní,“Òórùn ọmọ mi dàbí òórùn oko tí OLUWA ti bukun. +Kí Ọlọrun fún ọ ninu ìrì ọ̀runati ilẹ̀ tí ó dáraati ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini. +Kí àwọn eniyan máa sìn ọ́, kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹríba fún ọ.Ìwọ ni o óo máa ṣe olórí àwọn arakunrin rẹ,àwọn ọmọ ìyá rẹ yóo sì máa tẹríba fún ọ.Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé ọ, òun ni èpè yóo mọ́,ẹnikẹ́ni tí ó bá sì súre fún ọ, ìre yóo mọ́ ọn.” +Kó àwọn ohun ọdẹ rẹ: ọrun ati ọfà rẹ, lọ sí ìgbẹ́, kí o sì pa ẹran wá fún mi. +Bí Isaaki ti súre fún Jakọbu tán, Jakọbu fẹ́rẹ̀ má tíì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí Esau ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi ti oko ọdẹ dé. +Òun náà se oúnjẹ aládùn, ó gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó wí fún un pé, “Baba mi, dìde, kí o jẹ ninu ẹran tí èmi ọmọ rẹ pa, kí o lè súre fún mi.” +Isaaki, baba rẹ̀ bi í pé, “Ìwọ ta ni?” Esau bá dá a lóhùn pé, “Èmi ọmọ rẹ ni. Èmi, Esau, àkọ́bí rẹ.” +Ara Isaaki bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n gidigidi, ó wí pé, “Ta ló ti kọ́ pa ẹran tí ó gbé e tọ̀ mí wá, tí mo jẹ gbogbo rẹ̀ tán kí o tó dé? Mo sì ti súre fún un. Láìsí àní àní, ìre náà yóo mọ́ ọn.” +Nígbà tí Esau gbọ́ ohun tí baba rẹ̀ sọ, ó fi igbe ta, ó sọkún kíkorò, ó wí pé, “Baba mi, súre fún èmi náà.” +Ṣugbọn Isaaki dáhùn pé, “Àbúrò rẹ ti wá pẹlu ẹ̀tàn, ó sì ti gba ìre rẹ lọ.” +Esau bá dáhùn pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ̀ nítòótọ́. Ó di ìgbà keji tí yóo fi èrú gba ohun tíí ṣe tèmi. Ó ti kọ́kọ́ gba ipò àgbà lọ́wọ́ mi, ó tún wá jí ìre mi gbà lọ.” Esau bá bèèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Ṣé o kò wá fi ẹyọ ìre kan pamọ́ fún mi ni?” +Isaaki dá a lóhùn, ó ní, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ni mo sì ti fún un láti fi ṣe iranṣẹ, mo ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọkà ati ọtí waini. Kí ló tún wá kù tí mo lè ṣe fún ọ, ọmọ mi?” +Esau bẹ̀rẹ̀ sí bẹ baba rẹ̀ pé, “Ṣé ìre kan ṣoṣo ni o ní lẹ́nu ni, baba mi? Áà! Súre fún èmi náà, baba mi.” Esau bá bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. +Nígbà náà ni Isaaki, baba rẹ̀, dá a lóhùn, ó ní,“Níbi tí ilẹ̀ kò ti lọ́ràá ni o óo máa gbé,níbi tí kò sí ìrì ọ̀run. +Lẹ́yìn náà, se irú oúnjẹ aládùn tí mo fẹ́ràn fún mi, kí n jẹ ẹ́, kí ọkàn mi lè súre fún ọ kí n tó kú.” +Pẹlu idà rẹ ni o óo fi wà láàyè, arakunrin rẹ ni o óo sì máa sìn,ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, o óo já ara rẹ gbà,o óo sì bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.” +Nítorí irú ìre tí baba wọn sú fún Esau yìí ni Esau ṣe kórìíra Jakọbu. Esau dá ara rẹ̀ lọ́kàn le ó ní, “Ìgbà mélòó ni ó kù tí baba wa yóo fi kú? Bí ó bá ti kú ni n óo pa Jakọbu, arakunrin mi.” +Ṣugbọn wọ́n sọ ohun tí Esau, àkọ́bí Rebeka ń wí fún Rebeka ìyá rẹ̀. Rebeka bá ranṣẹ pe Jakọbu, ó wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀, Esau ẹ̀gbọ́n rẹ ń dá ara rẹ̀ lọ́kàn le pẹlu ìpinnu láti pa ọ́. +Nítorí náà, ọmọ mi, gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí, wá gbéra kí o sálọ bá Labani, arakunrin mi, ní Harani. +Kí o sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ títí tí inú tí ń bí arakunrin rẹ yóo fi rọ̀, +tí inú rẹ̀ yóo yọ́, tí yóo sì gbàgbé ohun tí o ti ṣe sí i, n óo wá ranṣẹ pè ọ́ pada nígbà náà. Mo ha gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ ẹ̀yin mejeeji lọ́jọ́ kan náà bí?” +Rebeka sọ fún Isaaki, ó ní, “Ọ̀rọ̀ àwọn obinrin Hiti wọnyi mú kí ayé sú mi. Bí Jakọbu bá lọ fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin ará Hiti, irú àwọn obinrin ilẹ̀ yìí, irú ire wo ni ó tún kù fún mi láyé mọ́?” +Ní gbogbo ìgbà tí Isaaki ń bá Esau ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, Rebeka ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ. Nítorí náà nígbà tí Esau jáde lọ sinu ìgbẹ́, +Rebeka pe Jakọbu ọmọ rẹ̀, ó sọ fún un, ó ní, “Mo gbọ́ tí baba yín ń bá Esau ẹ̀gbọ́n rẹ sọ̀rọ̀, +pé kí ó lọ pa ẹran wá fún òun, kí ó sì se oúnjẹ aládùn kí òun lè jẹ ẹ́, kí òun sì súre fún un níwájú OLUWA kí òun tó kú. +Nítorí náà, ọmọ mi, fetí sílẹ̀ kí o sì ṣe ohun tí n óo sọ fún ọ. +Lọ sinu agbo ẹran rẹ, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ meji tí ó lọ́ràá wá, kí n fi se irú oúnjẹ aládùn tí baba yín fẹ́ràn fún un, +Isaaki Súre fún Jakọbu. +Isaaki bá pe Jakọbu, ó súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ fẹ́ ninu àwọn ọmọbinrin ará Kenaani. +Jakọbu kúrò ní Beeriṣeba, ó ń lọ sí Harani. +Nígbà tí ó dé ibìkan tí ó rí i pé ilẹ̀ ti ń ṣú, ó gbé ọ̀kan ninu àwọn òkúta tí ó wà níbẹ̀, ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn. +Nígbà tí ó sùn, ó lá àlá kan, ó rí àkàsọ̀ kan lójú àlá, wọ́n gbé e kalẹ̀, orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run. Ó wá rí i tí àwọn angẹli Ọlọrun ń gùn ún lọ sókè sódò. +OLUWA pàápàá dúró lókè rẹ̀, ó wí fún un pé, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun Abrahamu baba rẹ ati Ọlọrun Isaaki, ilẹ̀ tí o dùbúlẹ̀ sí yìí, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi fún. +Àwọn ọmọ rẹ yóo pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, o óo sì gbilẹ̀ káàkiri sí ìhà ìwọ̀ oòrùn ati sí ìhà ìlà oòrùn, sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù nípasẹ̀ rẹ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo bukun aráyé. +Wò ó, mo wà pẹlu rẹ, n óo pa ọ́ mọ́ níbikíbi tí o bá lọ, n óo sì mú ọ pada wá sí ilẹ̀ yìí, nítorí pé n kò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí tí n óo fi ṣe gbogbo ohun tí mo sọ fún ọ.” +Nígbà tí Jakọbu tají ní ojú oorun rẹ̀, ó ní, “Dájúdájú OLUWA ń bẹ níhìn-ín, n kò sì mọ̀!” +Ẹ̀rù bà á, ó sì wí pé, “Ààrin yìí mà tilẹ̀ bani lẹ́rù pupọ o! Ibí yìí kò lè jẹ́ ibòmíràn bíkòṣe ilé Ọlọrun, ibí gan-an ni ẹnu ibodè ọ̀run.” +Jakọbu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí nàró gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀n, ó sì da òróró sórí rẹ̀. +Ó sọ ibẹ̀ ní Bẹtẹli, ṣugbọn Lusi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí. +Ó ní, “Dìde, lọ sí ilé Betueli, baba ìyá rẹ, ní Padani-aramu, kí o sì fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Labani, arakunrin ìyá rẹ. +Jakọbu bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan, ó ní “Bí Ọlọrun bá wà pẹlu mi, bí ó bá sì pa mí mọ́ ní ọ̀nà ibi tí mò ń lọ yìí, tí ó bá fún mi ní oúnjẹ jẹ, tí ó sì fún mi ni aṣọ wọ̀, +tí mo bá sì pada dé ilé baba mi ní alaafia, OLUWA ni yóo máa jẹ́ Ọlọrun mi. +Òkúta tí mo sì gbé nàró bí ọ̀wọ̀n yìí yóo di ilé Ọlọrun, n óo sì fún ìwọ Ọlọrun ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí o bá fún mi.” +Ọlọrun Olodumare yóo bukun ọ, yóo fún ọ ní ọmọ pupọ, yóo sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá. +Ìre tí ó sú fún Abrahamu yóo mọ́ ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ lórí. Ilẹ̀ tí ó fún Abrahamu, níbi tí Abrahamu ti jẹ́ àjèjì yóo sì di tìrẹ.” +Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki ṣe rán Jakọbu jáde lọ sí Padani-aramu lọ́dọ̀ Labani, ọmọ Betueli, ará Aramea, arakunrin Rebeka, ìyá Jakọbu ati Esau. +Esau rí i pé Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán an lọ sí Padani-aramu kí ó lọ fẹ́ iyawo, ati pé nígbà tí ó ń súre fún un, ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ fẹ́ ninu àwọn ọmọbinrin ará Kenaani. +Ó sì tún rí i pé Jakọbu gbọ́ ti baba ati ìyá rẹ̀, ó lọ sí Padani-aramu bí wọ́n ti sọ, +ati pé inú Isaaki, baba wọn kò dùn sí i pé kí wọn fẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kenaani níyàwó. +Nítorí náà Esau lọ sọ́dọ̀ Iṣimaeli ọmọ Abrahamu, ó sì fẹ́ Mahalati ọmọ rẹ̀, tíí ṣe arabinrin Nebaiotu, ó fi kún àwọn aya tí ó ti ní. +Esau Fẹ́ Aya Mìíràn. +Jakọbu tún ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, nígbà tí ó ṣe, ó dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà oòrùn. +Nígbà tí Jakọbu rí Rakẹli, ọmọ Labani, tíí ṣe arakunrin ìyá rẹ̀, ati agbo aguntan Labani, ó yí òkúta náà kúrò lẹ́nu kànga, ó sì pọn omi fún wọn. +Jakọbu bá fi ẹnu ko Rakẹli lẹ́nu, ó sì bú sẹ́kún. +Ó sọ fún Rakẹli pé, ìbátan baba rẹ̀ ni òun jẹ́, ati pé ọmọ Rebeka ni òun.Rakẹli bá sáré lọ sọ fún baba rẹ̀. +Nígbà tí Labani gbọ́ ìròyìn ayọ̀ náà pé, Jakọbu ọmọ arabinrin òun dé, ó sáré lọ pàdé rẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì mú un wá sí ilé. Jakọbu ròyìn ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ fún Labani. +Labani bá dá a lọ́kàn le, ó ní, “Láìsí àní àní, ẹ̀jẹ̀ kan náà ni wá” Jakọbu sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún oṣù kan. +Lẹ́yìn náà Labani sọ fún un pé, “O wá gbọdọ̀ máa sìn mí lásán nítorí pé o jẹ́ ìbátan mi? Sọ fún mi, èló ni o fẹ́ máa gbà?” +Labani ní ọmọbinrin meji, èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Lea, èyí àbúrò sì ń jẹ́ Rakẹli. +Ojú Lea kò fi bẹ́ẹ̀ fanimọ́ra, ṣugbọn Rakẹli jẹ́ arẹwà, ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra. +Jakọbu nífẹ̀ẹ́ Rakẹli, nítorí náà, ó sọ fún Labani pé, “N óo sìn ọ́ ní ọdún meje nítorí Rakẹli, ọmọ rẹ kékeré.” +Labani bá dá a lóhùn pé, “Ó tẹ́ mi lọ́rùn láti fún ọ ju kí n fún ẹni ẹlẹ́ni lọ. Máa bá mi ṣiṣẹ́.” +Bí ó ti gbójú sókè, ó rí kànga kan ninu pápá, ati agbo aguntan mẹta tí wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, nítorí pé láti inú kànga yìí ni wọ́n ti ń fún àwọn aguntan náà ní omi mu. Òkúta tí wọ́n sì yí dí ẹnu kànga náà tóbi pupọ. +Jakọbu bá sin Labani fún ọdún meje nítorí Rakẹli, ó sì dàbí ọjọ́ mélòó kan lójú rẹ̀ nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí Rakẹli. +Nígbà tí ó yá, Jakọbu sọ fún Labani pé, “Fún mi ní aya mi, kí á lè ṣe igbeyawo, nítorí ọjọ́ ti pé.” +Labani bá pe gbogbo àwọn ọkunrin ibẹ̀ jọ, ó se àsè ńlá fún wọn. +Ṣugbọn nígbà tí ó di àṣáálẹ́, Lea ni wọ́n mú wá fún Jakọbu dípò Rakẹli, Jakọbu sì bá a lòpọ̀. +Labani fi Silipa ẹrubinrin rẹ̀ fún Lea pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún un. +Nígbà tí ó di òwúrọ̀, Jakọbu rí i pé Lea ni wọ́n mú wá fún òun. Ó bi Labani, ó ní, “Irú kí ni o ṣe sí mi yìí? Ṣebí nítorí Rakẹli ni mo fi sìn ọ́? Èéṣe tí o tàn mí jẹ?” +Labani dáhùn, ó ní, “Ní ilẹ̀ tiwa níhìn-ín, àwa kì í fi àbúrò fọ́kọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n. +Fara balẹ̀ parí àwọn ètò ọ̀sẹ̀ igbeyawo ti eléyìí, n óo sì fún ọ ní ekeji náà, ṣugbọn o óo tún sìn mí ní ọdún meje sí i.” +Jakọbu gbà bẹ́ẹ̀, ó ṣe ọ̀sẹ̀ igbeyawo Lea parí, lẹ́yìn náà Labani fa Rakẹli, ọmọ rẹ̀ fún un. +Labani fi Biliha, ẹrubinrin rẹ̀ fún Rakẹli, ọmọbinrin rẹ̀, pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún un. +Nígbà tí gbogbo àwọn olùṣọ́-aguntan bá da aguntan wọn dé ìdí kànga yìí ni wọ́n tó ń yí òkúta náà kúrò lẹ́nu kànga. Lẹ́yìn náà, wọn á fún àwọn aguntan wọ́n lómi mu, wọ́n á sì yí òkúta náà pada sẹ́nu kànga. +Jakọbu bá Rakẹli náà lòpọ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ju Lea lọ, ó sì sin Labani fún ọdún meje sí i. +Nígbà tí OLUWA rí i pé Jakọbu kò fẹ́ràn Lea, ó fún Lea ní ọmọ bí, ṣugbọn Rakẹli yàgàn. +Lea lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Reubẹni, ó ní, “Nítorí OLUWA ti ṣíjú wo ìpọ́njú mi; nisinsinyii, ọkọ mi yóo fẹ́ràn mi.” +Ó tún lóyún, ó tún bí ọkunrin, ó ní, “Nítorí pé OLUWA ti gbọ́ pé wọ́n kórìíra mi ni ó ṣe fún mi ní ọmọ yìí pẹlu.” Ó bá sọ ọ́ ní Simeoni. +Ó tún lóyún, ó sì tún bí ọkunrin, ó ní, “Ọkọ mi gbọdọ̀ faramọ́ mi wàyí, nítorí pé ó di ọkunrin mẹta tí mo bí fún un”, nítorí náà, ó sọ ọmọ náà ní Lefi. +Ó tún lóyún ó sì tún bí ọkunrin, ó ní, “Wàyí o, n óo yin OLUWA,” ó bá sọ ọ́ ní Juda. Lẹ́yìn rẹ̀, kò bímọ mọ́. +Jakọbu bá bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ̀yin arakunrin mi, níbo ni ẹ ti wá?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Harani ni.” +Ó tún bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Labani ọmọ Nahori?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “A mọ̀ ọ́n.” +Ó tún bi wọ́n pé, “Ṣé alaafia ni ó wà?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, wò ó, Rakẹli, ọmọbinrin rẹ̀, ni ó ń da aguntan bọ̀ ní ọ̀kánkán yìí.” +Jakọbu sọ pé, “Oòrùn ṣì wà lókè, kò tíì tó àkókò láti kó àwọn ẹran jọ sójú kan, ẹ tètè fún àwọn aguntan ní omi mu, kí ẹ sì dà wọ́n pada lọ jẹ koríko sí i.” +Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò ṣeéṣe, àfi bí gbogbo àwọn olùṣọ́-aguntan bá dé tán, tí a bá yí òkúta kúrò lórí kànga, nígbà náà ni a tó lè fún àwọn aguntan ní omi mu.” +Bí ó ti ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rakẹli dé pẹlu agbo aguntan baba rẹ̀, nítorí pé òun ni ó ń tọ́jú wọn. +Jakọbu Dé sí Ilé Labani. +Ejò jẹ́ alárèékérekè ju gbogbo ẹranko tí OLUWA Ọlọrun dá lọ. Ejò bi obinrin náà pé, “Ngbọ́! Ṣé nítòótọ́ ni Ọlọrun sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso àwọn igi ọgbà yìí?” +Ó dá Ọlọrun lóhùn, ó ní, “Nígbà tí mo gbúròó rẹ ninu ọgbà, ẹ̀rù bà mí, mo bá farapamọ́ nítorí pé ìhòòhò ni mo wà.” +Ọlọrun bi í pé, “Ta ló sọ fún ọ pé ìhòòhò ni o wà? Àbí o ti jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ?” +Ọkunrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin tí o fi tì mí ni ó fún mi ninu èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.” +OLUWA Ọlọrun bi obinrin náà pé, “Irú kí ni o dánwò yìí?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Ejò ni ó tàn mí tí mo fi jẹ ẹ́.” +OLUWA Ọlọrun bá sọ fún ejò náà pé,“Nítorí ohun tí o ṣe yìí,o di ẹni ìfibú jùlọ láàrin gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko.Àyà rẹ ni o óo máa fi wọ́ káàkiri,erùpẹ̀ ni o óo sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. +N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà, ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀.Wọn óo máa fọ́ ọ lórí,ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.” +Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí fún obinrin náà pé,“N óo fi kún ìnira rẹ nígbà tí o bá lóyún,ninu ìrora ni o óo máa bímọ.Sibẹsibẹ, lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóo máa fà sí,òun ni yóo sì máa ṣe olórí rẹ.” +Ó sọ fún Adamu, pé,“Nítorí pé o gba ohun tí aya rẹ wí fún ọ,o sì jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ,mo fi ilẹ̀ gégùn-ún títí lae nítorí rẹ.Pẹlu ìnira ni o óo máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. +Ẹ̀gún ati òṣùṣú ni ilẹ̀ yóo máa hù jáde fún ọ, ewéko ni o óo sì máa jẹ. +Iṣé�� àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ,títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀,nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá.Erùpẹ̀ ni ọ́,o óo sì pada di erùpẹ̀.” +Obinrin náà dá a lóhùn, ó ní: “A lè jẹ ninu èso àwọn igi tí wọ́n wà ninu ọgbà, +Adamu sọ iyawo rẹ̀ ní Efa, nítorí pé òun ni ìyá gbogbo eniyan. +OLUWA Ọlọrun fi awọ ẹranko rán aṣọ fún Adamu ati iyawo rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n. +Lẹ́yìn náà, OLUWA Ọlọrun wí pé, “Nisinsinyii tí ọkunrin náà ti dàbí wa, tí ó sì ti mọ ire yàtọ̀ sí ibi, kí ó má lọ mú ninu èso igi ìyè, kí ó jẹ ẹ́, kí ó sì wà láàyè títí lae.” +Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde. +Ó lé e jáde, ó sì fi Kerubu kan sí ìhà ìlà oòrùn ọgbà náà láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè náà, pẹlu idà oníná tí ń jò bùlà bùlà, tí ó sì ń yí síhìn-ín sọ́hùn-ún. +àfi igi tí ó wà láàrin ọgbà nìkan ni Ọlọrun ní a kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso rẹ̀, a kò tilẹ̀ gbọdọ̀ fọwọ́ kàn án, ati pé ọjọ́ tí a bá fọwọ́ kàn án ni a óo kú.” +Ṣugbọn ejò náà dáhùn, ó ní, “Ẹ kò ní kú rárá, +Ọlọrun sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé bí ẹ bá jẹ ẹ́, ojú yín yóo là, ẹ óo sì dàbí òun alára, ẹ óo mọ ire yàtọ̀ sí ibi.” +Nígbà tí obinrin yìí ṣe akiyesi pé èso igi náà dára fún jíjẹ ati pé ó dùn ún wò, ó sì wòye bí yóo ti dára tó láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ó mú ninu èso igi náà, ó jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ náà sì jẹ ẹ́. +Ojú àwọn mejeeji bá là, wọ́n sì mọ̀ pé ìhòòhò ni àwọn wà, wọ́n bá gán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sán an mọ́ ìdí. +Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbúròó OLUWA Ọlọrun tí ń rìn ninu ọgbà. Wọ́n bá sá pamọ́ sí ààrin àwọn igi ọgbà. +Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun pe ọkunrin náà, ó bi í pé, “Níbo ni o wà?” +Ìwà Àìgbọràn. +Nígbà tí Rakẹli rí i pé òun kò bímọ fún Jakọbu rárá, ó bẹ̀rẹ̀ sí jowú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó wí fún Jakọbu pé, “Tí o kò bá fẹ́ kí n kú sí ọ lọ́rùn, fún mi lọ́mọ.” +Iranṣẹbinrin Lea bí ọmọkunrin kan fún Jakọbu. +Lea bá sọ pé, “Oríire.” Ó bá sọ ọmọ náà ní Gadi. +Iranṣẹbinrin Lea tún bí ọmọkunrin mìíràn fún Jakọbu. +Lea bá ní, “Mo láyọ̀, nítorí pé àwọn obinrin yóo máa pè mí ní Ẹni-Ayọ̀,” nítorí náà ó sọ ọmọ náà ní Aṣeri. +Ní àkókò ìkórè ọkà alikama, Reubẹni bá wọn lọ sí oko, ó sì já èso mandiraki bọ̀ fún Lea ìyá rẹ̀. Nígbà tí Rakẹli rí i, ó bẹ Lea pé kí ó fún òun ninu èso mandiraki ọmọ rẹ̀. +Ṣugbọn Lea dá a lóhùn pé, “O gba ọkọ mọ́ mi lọ́wọ́, kò tó ọ, o tún fẹ́ gba èso mandiraki ọmọ mi lọ́wọ́ mi?” Rakẹli bá dá a lóhùn, ó ní: “Bí o bá fún mi ninu èso mandiraki ọmọ rẹ, ọ̀dọ̀ rẹ ni Jakọbu yóo sùn lálẹ́ òní.” +Ní ìrọ̀lẹ́, nígbà tí Jakọbu ti oko dé, Lea jáde lọ pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Ọ̀dọ̀ mi ni o gbọdọ̀ sùn ní alẹ́ òní, èso mandiraki ọmọ mi ni mo fi san owó ọ̀yà rẹ. Jakọbu bá sùn lọ́dọ̀ rẹ̀ di ọjọ́ keji.” +Ọlọrun gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Lea, ó lóyún, ó bí ọmọkunrin karun-un. +Lea ní “Ọlọrun san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo fún ọkọ mi ní iranṣẹbinrin mi.” Ó bá sọ ọmọ náà ní Isakari. +Lea tún lóyún, ó bí ọkunrin kẹfa. +Inú bí Jakọbu pupọ sí ọ̀rọ̀ tí Rakẹli sọ, ó dá a lóhùn pé, “Ṣé èmi ni Ọlọrun tí kò fún ọ lọ́mọ ni?” +Ó ní, “Ọlọrun ti fi ẹ̀bùn rere fún mi, nígbà yìí ni ọkọ mi yóo tó bu ọlá fún mi, nítorí pé mo bí ọkunrin mẹfa fún un,” nítorí náà ó sọ ọmọ náà ní Sebuluni. +Lẹ́yìn náà, ó bí obinrin kan, ó sọ ọ́ ní Dina. +Lẹ́yìn náà ni Ọlọrun ranti Rakẹli, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣí inú rẹ̀. +Rakẹli lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. +Ó wí pé, “Ọlọrun ti mú ẹ̀gàn mi kúrò,” ó sọ ọmọ náà ní Josẹfu; ó ní, “Kí OLUWA má ṣàì fún mi ní ọmọkunrin mìíràn.” +Lẹ́yìn tí Rakẹli bí Josẹfu, Jakọbu tọ Labani lọ, ó bẹ̀ ẹ́ pé “Jẹ́ kí n pada sí ilé mi. +Jẹ́ kí àwọn aya ati àwọn ọmọ mi máa bá mi lọ, nítorí wọn ni mo ṣe sìn ọ́. Jẹ́ kí n máa lọ, ìwọ náà ṣá mọ̀ bí mo ti sìn ọ́ tó.” +Ṣugbọn Labani dá a lóhùn pé, “Gbà mí láàyè kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí, mo ti ṣe àyẹ̀wò, mo sì ti rí i pé nítorí tìrẹ ni OLUWA ṣe bukun mi, +sọ iye tí o bá fẹ́ máa gbà, n óo sì máa san án fún ọ.” +Jakọbu bá dáhùn pé, “Ìwọ náà mọ̀ bí mo ti sìn ọ́ ati bí àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ ti ṣe dáradára lọ́wọ́ mi. +Rakẹli bá dáhùn, ó ní, “Biliha, iranṣẹbinrin mi nìyí, bá a lòpọ̀, kí ó bímọ sí mi lọ́wọ́, kí èmi náà sì lè ti ipa rẹ̀ di ọlọ́mọ.” +Ẹran ọ̀sìn díẹ̀ ni o ní kí n tó dé ọ̀dọ̀ rẹ, díẹ̀ náà ti di pupọ nisinsinyii OLUWA ti bukun ọ ní gbogbo ọ̀nà nítorí tèmi. Nígbà wo ni èmi gan-an yóo tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àkójọ àwọn ohun tí mo lè pè ní tèmi?” +Labani bá bi í léèrè pé, “Kí ni kí n máa fún ọ?” Jakọbu dáhùn pé, “Má fún mi ní ohunkohun, bí o bá gbà láti ṣe ohun kan fún mi, n óo tún máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ. +Jẹ́ kí n bọ́ sí ààrin àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ lónìí, kí n sì ṣa gbogbo ọmọ aguntan dúdú, ati gbogbo ọmọ ewúrẹ́ ati aguntan tí ó ní dúdú tóótòòtóó lára, tí ó dàbí adíkálà, irú àwọn ẹran wọnyi ni n óo máa gbà fún iṣẹ́ tí mò ń ṣe fún ọ. +Bẹ́ẹ̀ ni òdodo mi yóo jẹ́rìí gbè mí ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí o bá wá wo ọ̀yà mi. Èyíkéyìí tí kò bá jẹ́ dúdú ninu àwọn aguntan, tabi ewúrẹ́ tí àwọ̀ rẹ̀ kò bá ní dúdú tóótòòtóó tí o bá rí láàrin àwọn ẹran mi, a jẹ́ pé mo jí i gbé ni.” +Labani bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, ohun tí o wí gan-an ni a óo ṣe.” +Ṣugbọn ní ọjọ́ náà gan-an ni Labani ṣa gbogbo ewúrẹ́ ati òbúkọ tí àwọ̀ wọn ní funfun tóótòòtóó, tabi tí ó dàbí adíkálà, ati gbogbo àwọn tí wọ́n ní funfun lára, ati gbogbo àwọn aguntan dúdú, ó kó wọn lé àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. +Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá kó wọn lọ jìnnà sí Jakọbu, ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta. Jakọbu bá ń tọ́jú agbo ẹran Labani tí ó kù. +Jakọbu gé ọ̀pá igi populari ati ti alimọndi, ati ti pilani tútù, ó bó àwọn ọ̀pá náà ní àbófín, ó jẹ́ kí funfun wọn hàn síta. +Ó to àwọn ọ̀pá wọnyi siwaju àwọn ẹran níbi tí wọ́n ti ń mu omi, nítorí pé, nígbà tí wọ́n bá wá mu omi ni wọ́n máa ń gùn. +Àwọn ẹran náà ń gun ara wọn níwájú àwọn ọ̀pá wọnyi, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bí ọmọ tí àwọ̀ wọn dàbí adíkálà ati àwọn tí wọ́n ní funfun tóótòòtóó. +Ó bá fún Jakọbu ní Biliha, iranṣẹbinrin rẹ̀ kí ó fi ṣe aya, Jakọbu sì bá a lòpọ̀. +Jakọbu ṣa àwọn ọmọ aguntan wọnyi sọ́tọ̀, ó sì tún mú kí gbogbo agbo ẹran Labani dojú kọ àwọn ẹran tí àwọ̀ wọn ní funfun tóótòòtóó tabi tí ó dàbí adíkálà, tabi àwọn tí wọ́n jẹ́ dúdú, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣa àwọn ẹran tirẹ̀ sinu agbo kan lọ́tọ̀, kò pa wọ́n pọ̀ pẹlu ti Labani. +Nígbà tí àwọn ẹran tí ara wọ́n le dáradára láàrin agbo bá ń gùn, Jakọbu a fi àwọn ọ̀pá náà siwaju wọn, kí wọ́n lè máa gùn láàrin wọn. +Ṣugbọn nígbà tí àwọn ẹran tí kò lókun ninu tóbẹ́ẹ̀ bá ń gùn, kì í fi àwọn ọ̀pá náà siwaju wọn, báyìí ni àwọn ẹran tí kò lókun ninu di ti Labani, àwọn tí wọ́n lókun ninu sì di ti Jakọbu. +Bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu ṣe di ọlọ́rọ̀ gidigidi, ó sì ní àwọn agbo ẹran ńláńlá, ọpọlọpọ iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin, ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. +Biliha lóyún, ó bí ọmọkunrin kan fún Jakọbu. +Rakẹli bá sọ pé, “Ọlọrun dá mi láre, ó gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ní ọmọkunrin kan.” Nítorí náà, ó sọ ọmọ náà ní Dani. +Biliha, iranṣẹbinrin Rakẹli tún lóyún, ó bí ọmọkunrin keji fún Jakọbu. +Rakẹli bá sọ pé, “Ìjàkadì gidi ni mo bá ẹ̀gbọ́n mi jà, mo sì ṣẹgun,” ó sì sọ ọmọ náà ní Nafutali. +Nígbà tí Lea rí i pé òun kò bímọ mọ́, ó fún Jakọbu ní Silipa, iranṣẹbinrin rẹ̀, kí ó fi ṣe aya. +Jakọbu Dúnàá Dúrà pẹlu Labani. +Jakọbu gbọ́ pé àwọn ọmọ Labani ń sọ pé òun ti gba gbogbo ohun tíí ṣe ti baba wọn, ninu ohun ìní baba wọn ni òun sì ti kó gbogbo ọrọ̀ òun jọ. +“Ní àkókò tí àwọn ẹran náà ń gùn, mo rí i lójú àlá pé àwọn òbúkọ tí wọn ń gun àwọn ẹran jẹ́ àwọn tí àwọ̀ wọn dàbí ti adíkálà ati àwọn onífunfun tóótòòtóó ati àwọn abilà. +Angẹli Ọlọrun bá sọ fún mi ní ojú àlá náà, ó ní, ‘Jakọbu.’ Mo dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’ +Angẹli Ọlọrun bá sọ pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò ó pé gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran inú agbo jẹ́ aláwọ̀ adíkálà ati onífunfun tóótòòtóó ati abilà, nítorí mo ti rí gbogbo ohun tí Labani ń ṣe sí ọ. +Èmi ni Ọlọrun Bẹtẹli, níbi tí o ti ta òróró sórí òkúta tí o sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún mi. Dìde nisinsinyii, kí o jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí, kí o sì pada sí ilẹ̀ tí wọ́n gbé bí ọ.’ ” +Ni Rakẹli ati Lea bá dá a lóhùn pé, “Ǹjẹ́ ogún kan tilẹ̀ tún kù fún wa ní ilé baba wa mọ́? +Ǹjẹ́ kò ti kà wá kún àjèjì? Nítorí pé ó ti tà wá, ó sì ti ná owó tí ó gbà lórí wa tán. +Ti àwa ati àwọn ọmọ wa ni ohun ìní gbogbo tí Ọlọrun gbà lọ́wọ́ baba wa jẹ́, nítorí náà, gbogbo ohun tí Ọlọrun bá sọ fún ọ láti ṣe, ṣe é.” +Jakọbu bá dìde, ó gbé àwọn ọmọ ati àwọn aya rẹ̀ gun ràkúnmí. +Ó bẹ̀rẹ̀ sí da gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí ó ti kó jọ ní Padani-aramu siwaju, ó ń pada lọ sọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ní ilẹ̀ Kenaani. +Ní àkókò yìí, Labani wà níbi tí ó ti ń gé irun àwọn aguntan rẹ̀, Rakẹli bá jí àwọn ère oriṣa ilé baba rẹ̀ kó. +Jakọbu pàápàá kíyèsí i pé Labani kò fi ojurere wo òun mọ́ bíi ti àtẹ̀yìnwá. +Ọgbọ́n ni Jakọbu lò fún Labani ará Aramea, nítorí pé Jakọbu kò sọ fún un pé òun fẹ́ sálọ. +Ó dìde, ó kó gbogbo ohun tí ó ní, ó sá gòkè odò Yufurate, ó doríkọ ọ̀nà agbègbè olókè Gileadi. +Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí wọ́n sọ fún Labani pé Jakọbu ti sálọ, +ó kó àwọn ìbátan rẹ̀, ó sì tọpa rẹ̀ fún ọjọ́ meje, ó bá a ní agbègbè olókè Gileadi. +Ṣugbọn Ọlọrun sọ fún Labani ará Aramea lóru lójú àlá, ó ní, “Ṣọ́ra, má bá Jakọbu sọ ohunkohun, kì báà jẹ́ rere tabi buburu.” +Labani lé Jakọbu bá níbi tí ó pàgọ́ rẹ̀ sí ní orí òkè náà, Labani ati àwọn ìbátan rẹ̀ sì pàgọ́ tiwọn sí agbègbè olókè Gileadi. +Labani pe Jakọbu, ó ní, “Èéṣe tí o fi ṣe báyìí? O tàn mí jẹ, o sì kó àwọn ọmọbinrin mi sá bí ẹrú tí wọ́n kó lójú ogun. +Èéṣe tí o fi tàn mí jẹ, tí o yọ́ lọ láìsọ fún mi? Ṣebí ǹ bá fi ayọ̀, ati orin ati ìlù ati hapu sìn ọ́. +Èéṣe tí o kò fún mi ní anfaani láti fi ẹnu ko àwọn ọmọ mi lẹ́nu kí n fi dágbére fún wọn? Ìwà òmùgọ̀ ni o hù yìí. +Mo ní agbára láti ṣe ọ́ níbi, ṣugbọn Ọlọrun baba rẹ bá mi sọ̀rọ̀ ní òru àná pé kí n ṣọ́ra, kí n má bá ọ sọ ohunkohun, kì báà jẹ́ rere tabi buburu. +Nígbà náà ni OLUWA sọ fún Jakọbu pé, “Pada lọ sí ilẹ̀ baba rẹ ati ti àwọn ìbátan rẹ, n óo sì wà pẹlu rẹ.” +Mo mọ̀ pé ọkàn rẹ fà sí ilé ni o fi sá, ṣugbọn, èéṣe tí o fi jí àwọn ère oriṣa mi kó?” +Jakọbu bá dá Labani lóhùn, ó ní, “Ẹ̀rù ni ó bà mí, mo rò pé o óo fi ipá gba àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ mi. +Ní ti àwọn ère oriṣa rẹ, bí o bá bá a lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, pípa ni a óo pa olúwarẹ̀. Níwájú gbogbo ìbátan wa, tọ́ka sí ohunkohun tí ó bá jẹ́ tìrẹ ninu gbogbo ohun tí ó wà lọ́dọ̀ mi, kí o sì mú un.” Jakọbu kò mọ̀ rárá pé Rakẹli ni ó jí àwọn ère oriṣa Labani kó. +Labani bá wá inú àgọ́ Jakọbu, ati ti Lea ati ti àwọn iranṣẹbinrin mejeeji, ṣugbọn kò rí àwọn ère oriṣa rẹ̀. Bí ó ti jáde ninu àgọ́ Lea ni ó lọ sí ti Rakẹli. +Rakẹli ni ó kó àwọn ère oriṣa náà, ó dì wọ́n sinu àpò gàárì ràkúnmí, ó sì jókòó lé e mọ́lẹ̀. Labani tú gbogbo inú àgọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò rí wọn. +Rakẹli wí fún baba rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́, oluwa mi, má bínú pé n kò dìde lójú kan tí mo jókòó sí, mò ń ṣe nǹkan oṣù mi lọ́wọ́ ni.” Bẹ́ẹ̀ ni Labani ṣe wá àwọn ère oriṣa rẹ̀ títí, ṣugbọn kò rí wọn. +Inú wá bí Jakọbu, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Labani, ó ní, “Kí ni mo ṣe? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ tí o fi ń tọpa mi kíkankíkan bẹ́ẹ̀? +Nígbà tí o tú gbogbo ẹrù mi palẹ̀, àwọn nǹkan rẹ wo ni o rí níbẹ̀? Kó o kalẹ̀ níwájú àwọn ìbátan mi ati àwọn ìbátan rẹ, kí wọ́n lè dájọ́ láàrin wa. +Fún ogún ọdún tí mo fi bá ọ gbé, ewúrẹ́ rẹ kan tabi aguntan kan kò sọnù rí, bẹ́ẹ̀ ni n kò jí àgbò rẹ kan pajẹ rí. +Èyí tí ẹranko burúkú bá pajẹ tí n kò bá gbé òkú rẹ̀ wá fún ọ, èmi ni mò ń fara mọ́ ọn. O máa ń gba ààrọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ mi, ìbáà jẹ́ ní òru ni ó sọnù tabi ní ọ̀sán. +Jakọbu bá ranṣẹ pe Rakẹli ati Lea sinu pápá níbi tí agbo ẹran rẹ̀ wà. +Bẹ́ẹ̀ ni mò ń wà ninu oòrùn lọ́sàn-án ati ninu òtútù lóru, oorun kò sì sí lójú mi. +Ó di ogún ọdún tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ, mo fi ọdún mẹrinla sìn ọ́ nítorí àwọn ọmọbinrin rẹ, ati ọdún mẹfa fún agbo ẹran rẹ. Ìgbà mẹ́wàá ni o sì pa owó ọ̀yà mi dà. +Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun baba mi wà pẹlu mi, àní, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun tí Isaaki ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù, láìsí àní àní, ìwọ ìbá ti lé mi lọ l��̣wọ́ òfo kó tó di àkókò yìí. Ọlọrun rí ìyà mi ati iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó fi kìlọ̀ fún ọ ní alẹ́ àná.” +Labani bá dá Jakọbu lóhùn, ó ní, “Èmi ni mo ni àwọn ọmọbinrin wọnyi, tèmi sì ni àwọn ọmọ wọnyi pẹlu, èmi náà ni mo ni àwọn agbo ẹran, àní gbogbo ohun tí ò ń wò wọnyi, èmi tí mo ni wọ́n nìyí. Ṣugbọn kí ni mo lè ṣe lónìí sí àwọn ọmọbinrin mi wọnyi ati sí àwọn ọmọ tí wọ́n bí? +Ó dára, jẹ́ kí èmi pẹlu rẹ dá majẹmu, kí majẹmu náà sì jẹ́ ẹ̀rí láàrin àwa mejeeji.” +Jakọbu bá gbé òkúta kan, ó fi sọlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀n. +Ó sì sọ fún àwọn ìbátan rẹ̀ kí wọ́n kó òkúta jọ. Wọ́n sì kó òkúta jọ, wọ́n fi ṣe òkítì ńlá kan, gbogbo wọn bá jọ jẹun níbi òkítì náà. +Labani sọ ibẹ̀ ní Jegari Sahaduta, ṣugbọn Jakọbu pè é ní Galeedi. +Labani wí pé, “Òkítì yìí ni ohun ẹ̀rí láàrin èmi pẹlu rẹ lónìí.” Nítorí náà ó sọ ọ́ ní Galeedi. +Ó sì sọ ọ̀wọ̀n náà ní Misipa, nítorí ó wí pé, “Kí OLUWA ṣọ́ wa nígbà tí a bá pínyà lọ́dọ̀ ara wa. +Ó wí fún wọn pé, “Mo ṣàkíyèsí pé baba yín kò fi ojurere wò mí bíi ti àtẹ̀yìnwá mọ́, ṣugbọn Ọlọrun baba mi wà pẹlu mi. +Bí o bá fi ìyà jẹ àwọn ọmọbinrin mi, tabi o tún fẹ́ obinrin mìíràn kún àwọn ọmọbinrin mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹnìkan pẹlu wa, ranti o, Ọlọrun ni ẹlẹ́rìí láàrin àwa mejeeji.” +Labani bá sọ fún Jakọbu pé, “Wo òkítì ati ọ̀wọ̀n yìí, tí mo ti gbé kalẹ̀ láàrin àwa mejeeji. +Òkítì yìí ati ọ̀wọ̀n yìí sì ni ẹ̀rí pẹlu pé n kò ní kọjá òkítì yìí láti wá gbógun tì ọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ náà kò ní kọjá òkítì ati ọ̀wọ̀n yìí láti wá gbógun tì mí. +Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Nahori, àní, Ọlọrun baba wọn ni onídàájọ́ láàrin wa.” Jakọbu náà bá búra ní orúkọ Ọlọrun tí Isaaki baba rẹ̀ ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. +Jakọbu bá rúbọ lórí òkè náà, ó pe àwọn ìbátan rẹ̀ láti jẹun, wọ́n sì wà lórí òkè náà ní gbogbo òru ọjọ́ náà. +Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Labani fi ẹnu ko àwọn ọmọbinrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu láti dágbére fún wọn, ó súre fún wọn, ó sì pada sílé. +Ẹ̀yin náà mọ̀ pé gbogbo agbára mi ni mo ti fi sin baba yín, +sibẹ, baba yín rẹ́ mi jẹ, ó sì yí owó ọ̀yà mi pada nígbà mẹ́wàá, ṣugbọn Ọlọrun kò gbà fún un láti pa mí lára. +Bí ó bá wí pé àwọn ẹran tí ó ní funfun tóótòòtóó ni yóo jẹ́ owó ọ̀yà mi, gbogbo ẹran inú agbo a sì bí onífunfun tóótòòtóó. Bí ó bá sì wí pé, àwọn ẹran tí ó bá ní àwọ̀ tí ó dàbí adíkálà ni yóo jẹ́ tèmi, gbogbo ẹran inú agbo a sì bí ọmọ tí àwọ̀ wọn dàbí adíkálà. +Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gba gbogbo ẹran baba yín tí ó sì fi wọ́n fún mi. +Jakọbu Sá kúrò lọ́dọ̀ Labani. +Bí Jakọbu ti ń lọ ní ojú ọ̀nà, àwọn angẹli Ọlọrun pàdé rẹ̀. +N kò lẹ́tọ̀ọ́ sí èyí tí ó kéré jùlọ ninu ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀, ati òdodo tí o ti fihan èmi iranṣẹ rẹ, nítorí ọ̀pá lásán ni mo mú lọ́wọ́ nígbà tí mo gòkè odò Jọdani, ṣugbọn nisinsinyii, mo ti di ẹgbẹ́ ogun ńlá meji. +Mo bẹ̀ ọ́, gbà mí lọ́wọ́ Esau arakunrin mi, nítorí ẹ̀rù rẹ̀ ń bà mí, kí ó má baà wá pa gbogbo wa, àtàwọn ìyá, àtàwọn ọmọ wọn. +Ìwọ ni o ṣá sọ fún mi pé, ‘Ire ni n óo ṣe fún ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí iyanrìn etí òkun tí ẹnikẹ́ni kò ní lè kà tán.’ ” +Ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà, ó sì mú ninu ohun ìní rẹ̀ láti fi ṣe ẹ̀bùn fún Esau arakunrin rẹ̀. +Ó ṣa igba (200) ewúrẹ́ ati ogún òbúkọ, igba (200) aguntan, ati ogún àgbò, +ọgbọ̀n abo ràkúnmí, tàwọn tọmọ wọn, ogoji abo mààlúù ati akọ mààlúù mẹ́wàá, ogún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati akọ mẹ́wàá. +Ó fi iranṣẹ kọ̀ọ̀kan ṣe olùtọ́jú agbo ẹran kọ̀ọ̀kan. Ó sọ fún àwọn iranṣẹ wọnyi pé, “Ẹ máa lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrin agbo ẹran kan ati ekeji.” +Ó sọ fún èyí tí ó ṣáájú patapata pé, “Nígbà tí Esau arakunrin mi bá pàdé rẹ, tí ó sì bi ọ́ pé, ‘Ti ta ni ìwọ í ṣe? Níbo ni ò ń lọ? Ta ló sì ni àwọn ẹran tí wọ́n wà níwájú rẹ?’ +Kí o wí pé, ‘Ti Jakọbu iranṣẹ rẹ ni, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀bùn tí ó fi ranṣẹ sí Esau oluwa rẹ̀, òun alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ” +Bákan náà ni ó kọ́ ekeji ati ẹkẹta ati gbogbo àwọn iranṣẹ tí wọ́n tẹ̀lé àwọn agbo ẹran náà. Ó ní, “Nǹkan kan náà ni kí ẹ máa wí fún Esau, nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀. +Nígbà tí Jakọbu rí wọn, ó ní, “Àwọn ọmọ ogun Ọlọrun nìyí.” Ó bá sọ ibẹ̀ ní Mahanaimu. +Kí ẹ sì wí pé, ‘Jakọbu alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ” Nítorí ó rò ninu ara rẹ̀ pé, bóyá òun lè fi àwọn ẹ̀bùn tí ó tì ṣáájú wọnyi tù ú lójú, àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, nígbà tí ojú àwọn mejeeji bá pàdé, bóyá yóo dáríjì òun. +Nítorí náà, àwọn ẹ̀bùn ni ó kọ́ lọ ṣáájú rẹ̀, òun pàápàá sì dúró ninu àgọ́ ní alẹ́ ọjọ́ náà. +Ní òru ọjọ́ náà gan an, ó dìde ó kó àwọn aya rẹ̀ mejeeji, àwọn iranṣẹbinrin mejeeji ati àwọn ọmọ rẹ̀ mọkọọkanla, ó kọjá sí ìhà keji odò Jaboku. +Ó kó àwọn ati ohun gbogbo tí ó ní kọjá sí ìhà keji odò. +Ó wá ku Jakọbu nìkan, ọkunrin kan bá a wọ ìjàkadì títí di àfẹ̀mọ́jú ọjọ́ keji. +Nígbà tí ọkunrin náà rí i pé òun kò lè dá Jakọbu, ó fi ọwọ́ kan kòtò itan rẹ̀, eegun itan Jakọbu bá yẹ̀ níbi tí ó ti ń bá a jìjàkadì. +Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí n lọ nítorí ilẹ̀ ti ń mọ́” Ṣugbọn Jakọbu kọ̀, ó ní, “N kò ní jẹ́ kí o lọ, àfi bí o bá súre fún mi.” +Ọkunrin náà bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Jakọbu dáhùn pé, “Jakọbu ni.” +Ọkunrin náà bá dáhùn pé, “A kò ní pè ọ́ ní Jakọbu mọ́, Israẹli ni a óo máa pè ọ́, nítorí pé o ti bá Ọlọrun ati eniyan wọ ìjàkadì, o sì ti ṣẹgun.” +Jakọbu bá bẹ̀ ẹ́, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣugbọn ó dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí o fi ń bèèrè orúkọ mi?” Ó bá súre fún Jakọbu níbẹ̀. +Jakọbu rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú lọ sọ́dọ̀ Esau, ẹ̀gbọ́n rẹ̀, tí ó wà ní ilẹ̀ Seiri, ní agbègbè Edomu. +Nítorí náà ni Jakọbu fi sọ ibẹ̀ ní Penieli, ó ní, “Mo ti rí Ọlọrun lojukooju, sibẹ mo ṣì wà láàyè.” +Oòrùn yọ kí ó tó kọjá Penueli, nítorí pé títiro ni ó ń tiro lọ nítorí itan rẹ̀. +Nítorí náà, títí di òní, àwọn ọmọ Israẹli kì í jẹ iṣan tí ó bo ihò itan níbi tí itan ti sopọ̀ mọ́ ìbàdí, nítorí pé ihò itan Jakọbu ni ọkunrin náà fọwọ́ kàn, orí iṣan tí ó so ó pọ̀ mọ́ ìbàdí. +Ó sọ fún wọn pé, “Ohun tí ẹ óo sọ fún Esau, oluwa mi nìyí, ẹ ní èmi, Jakọbu iranṣẹ rẹ̀, ní kí ẹ sọ fún un pé mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Labani, ati pé ibẹ̀ ni mo sì ti wà títí di àkókò yìí. +Ẹ ní mo ní àwọn mààlúù, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, agbo ẹran, àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin. Ẹ ní mo ní kí n kọ́ ranṣẹ láti sọ fún un ni, kí n lè rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ̀.” +Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ náà pada wá jábọ̀ fún Jakọbu, wọ́n sọ fún un pé, “A jíṣẹ́ rẹ fún Esau arakunrin rẹ, ó sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ pẹlu irinwo (400) ọkunrin.” +Ẹ̀rù ba Jakọbu gidigidi, ó sì dààmú, ó bá dá àwọn eniyan tí wọn wà pẹlu rẹ̀ ati agbo mààlúù, ati agbo aguntan ati àwọn ràkúnmí rẹ̀ sí ọ̀nà meji meji. +Ó rò ninu ara rẹ̀ pé bí Esau bá dé ọ̀dọ̀ ìpín tí ó wà níwájú, tí ó bá sì pa wọ́n run, ìpín kan tí ó kù yóo sá àsálà. +Jakọbu bá gbadura báyìí pé, “Ọlọrun Abrahamu baba mi, ati Ọlọrun Isaaki baba mi, Ọlọrun tí ó wí fún mi pé, ‘Pada sí ilẹ̀ rẹ ati sí ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, n óo sì ṣe ọ́ níre.’ +Jakọbu Múra láti Pàdé Esau. +Bí Jakọbu ti gbé ojú sókè, ó rí Esau tí ń bọ̀ pẹlu irinwo (400) ọkunrin. Ó bá pín àwọn ọmọ rẹ̀ fún Lea ati Rakẹli, ati àwọn iranṣẹbinrin mejeeji. +Ṣugbọn Jakọbu dáhùn pé, “Rárá o, jọ̀wọ́, bí mo bá bá ojurere rẹ pàdé nítòótọ́ gba ẹ̀bùn tí mo mú wá lọ́wọ́ mi, nítorí pé rírí tí mo rí ojú rẹ tí inú rẹ sì yọ́ sí mi tó báyìí, ó dàbí ìgbà tí mo rí ojú Ọlọrun. +Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn tí mo mú wá fún ọ nítorí pé Ọlọrun ti ṣe oore fún mi lọpọlọpọ ati pé mo ní ànító.” Jakọbu rọ̀ ọ́ títí tí ó fi gbà á. +Lẹ́yìn náà, Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jẹ́ kí á múra kí á máa lọ n óo sì ṣáájú.” +Ṣugbọn Jakọbu dá a lóhùn, ó ní, “Ṣebí oluwa mi mọ̀ pé àwọn ọmọ kò lágbára tóbẹ́ẹ̀ ati pé mo níláti ro ti àwọn ẹran tí wọ́n ní ọmọ wẹ́wẹ́ lẹ́yìn, bí a bá dà wọ́n ní ìdàkudà ní ọjọ́ kan péré, gbogbo agbo ni yóo run. +Oluwa mi, máa lọ níwájú, n óo máa bọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ níwọ̀n bí ìrìn àwọn ẹran ati àwọn ọmọ bá ti lè yá mọ, títí tí n óo fi wá bá oluwa mi ní Seiri.” +Esau bá ní, “Jẹ́ kí n fi àwọn bíi mélòó kan sílẹ̀ pẹlu rẹ ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi.” Ṣugbọn Jakọbu dá a lóhùn pé, “Mo dúpẹ́, má wulẹ̀ ṣe ìyọnu kankan. Àní, kí n ṣá ti rí ojurere oluwa mi.” +Esau bá yipada ní ọjọ́ náà, ó gbọ̀nà Seiri. +Ṣugbọn Jakọbu lọ sí Sukotu o kọ́ ilé kan fún ara rẹ̀ ó sì ṣe àtíbàbà fún àwọn ẹran rẹ̀. Nítorí náà ni wọ́n Ṣe ń pe ibẹ̀ ní Sukotu. +Nígbà tí ó yá, Jakọbu dé sí Ṣekemu ní ilẹ̀ Kenaani ní alaafia, nígbà tí ó ń pada ti Padani-aramu bọ̀ ó pàgọ́ rẹ̀ siwaju ìlú náà. +Ó ra ilẹ̀ ibi tí ó pàgọ́ rẹ̀ sí ní ọgọrun-un (100) gẹsita lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu. +Ó ti àwọn iranṣẹbinrin ati àwọn ọmọ wọn ṣáájú, Lea ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì tẹ̀lé wọn, Rakẹli ati Josẹfu ni wọ́n wà lẹ́yìn patapata. +Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sọ pẹpẹ náà ní Eli-Ọlọrun-Israẹli. +Jakọbu alára bá bọ́ siwaju gbogbo wọn, ó wólẹ̀ nígbà meje títí tí ó fi súnmọ́ Esau, arakunrin rẹ̀. +Esau sáré pàdé rẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó so mọ́ ọn lọ́rùn, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, àwọn mejeeji sì sọkún. +Nígbà tí Esau gbé ojú sókè, tí ó rí àwọn obinrin ati àwọn ọmọ, ó ní, “Ta ni àwọn wọnyi tí wọ́n wà pẹlu rẹ?”Jakọbu dáhùn, ó ní, “Àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi ta èmi iranṣẹ rẹ lọ́rẹ ni.” +Àwọn iranṣẹbinrin ati àwọn ọmọ wọn bá súnmọ́ wọn, wọ́n sì wólẹ̀ fún Esau. +Lea ati àwọn ọmọ rẹ̀ náà súnmọ́ wọn, àwọn náà wólẹ̀ fún un, lẹ́yìn náà ni Josẹfu ati Rakẹli súnmọ́ ọn, àwọn náà wólẹ̀ fún un bákan náà. +Ó bá bèèrè, ó ní, “Kí ni o ti fẹ́ ṣe gbogbo àwọn agbo ẹran tí mo pàdé lọ́nà?” Jakọbu dáhùn, ó ní, “Mo ní kí n fi wọ́n wá ojurere Esau, oluwa mi ni.” +Ṣugbọn Esau dáhùn pé, “Èyí tí mo ní ti tó mi, arakunrin mi, máa fi tìrẹ sọ́wọ́.” +Jakọbu Pàdé Esau. +Ní ọjọ́ kan, Dina, ọmọbinrin tí Lea bí fún Jakọbu jáde lọ kí àwọn obinrin kan ní ìlú Ṣekemu. +A óo jọ máa gbé pọ̀, ibi tí ó bá wù yín ni ẹ lè gbé, ibi tí ẹ bá fẹ́ ni ẹ ti lè ṣòwò, tí ẹ sì lè ní ohun ìní.” +Ṣekemu tún wí fún baba ati àwọn arakunrin omidan náà pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yọ́nú sí mi, ohunkohun tí ẹ bá ní kí n san, n óo san án. +Iyekíye tí ó bá wù yín ni kí ẹ bèèrè fún owó orí iyawo, n óo san án, ẹ ṣá ti fi omidan náà fún mi.” +Ọgbọ́n ẹ̀tàn ni àwọn ọmọ Jakọbu fi dá Ṣekemu ati Hamori, baba rẹ̀ lóhùn, nítorí bíbà tí ó ba Dina, arabinrin wọn jẹ́. +Wọ́n wí fún wọn pé, “Ìtìjú gbáà ni ó jẹ́, pé kí a fi ọmọbinrin wa fún ẹni tí kò kọlà abẹ́, a kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. +Ohun kan ṣoṣo tí ó lè mú kí ọ̀rọ̀ náà ṣeéṣe ni pé kí ẹ̀yin náà dàbí wa, kí gbogbo ọkunrin yín kọlà abẹ́. +Nígbà náà ni a óo tó máa fi ọmọ wa fun yín tí àwa náà yóo máa fẹ́ ọmọ yín, a óo máa gbé pọ̀ pẹlu yín, a óo sì di ọ̀kan. +Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò gbà láti kọlà abẹ́, a óo mú ọmọbinrin wa, a óo sì máa lọ.” +Ọ̀rọ̀ wọn dùn mọ́ Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀ ninu. +Ọdọmọkunrin náà kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀, nítorí pé ó fẹ́ràn ọmọbinrin Jakọbu lọpọlọpọ. Ninu gbogbo ìdílé ọmọkunrin yìí, òun ni ó jẹ́ eniyan pataki jùlọ. +Nígbà tí Ṣekemu ọmọ Hamori, ará Hifi, tíí ṣe ọmọ ọba ìlú náà rí i, ó fi ipá mú un, ó sì bá a lòpọ̀ tipátipá. +Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀ bá lọ sí ẹnubodè ìlú, wọ́n sọ fún àwọn ọkunrin ìlú náà pé, +“Ìbágbé àwọn eniyan wọnyi tuni lára pupọ, ẹ jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ wa, kí wọ́n máa tà, kí wọ́n máa rà, ilẹ̀ yìí tóbi tó, ó gbà wọ́n. Ẹ jẹ́ kí á máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn, kí àwọn náà sì máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wa. +Ohun kan ṣoṣo ni wọ́n ní kí á ṣe kí á lè jọ máa gbé pọ̀, kí á sì di ọ̀kan, wọ́n ní olukuluku ọkunrin wa gbọdọ̀ kọlà abẹ́ gẹ́gẹ́ bíi tiwọn. +Ṣebí gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo ohun ìní wọn ni yóo di tiwa? Ẹ ṣá jẹ́ kí á gbà fún wọn, wọn yóo sì máa bá wa gbé.” +Gbogbo àwọn ará ìlú náà gba ohun tí Hamori ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀ wí, gbogbo ọkunrin sì kọlà abẹ́. +Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí ará kan wọ́n, meji ninu àwọn ọmọ Jakọbu, Simeoni ati Lefi, arakunrin Dina, mú idà wọn, wọ́n jálu àwọn ará ìlú náà lójijì, wọ́n sì pa gbogbo ọkunrin wọn. +Wọ́n fi idà pa Hamori pẹlu, ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Wọ́n mú Dina jáde kúrò ní ilé Ṣekemu, wọ́n sì bá tiwọn lọ. +Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Jakọbu w�� kó gbogbo ohun ìní àwọn ará ìlú náà nítorí pé wọ́n ba arabinrin wọn jẹ́. +Wọ́n kó gbogbo aguntan wọn, gbogbo mààlúù wọn, gbogbo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, ati gbogbo ohun tí ó wà nílé ati èyí tí ó wà ninu pápá. +Ati gbogbo dúkìá wọn, àwọn ọmọ wọn ati àwọn aya wọn, gbogbo wọn ni wọ́n kó lẹ́rú, wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé wọn pẹlu. +Ọkàn rẹ̀ fà sí Dina ọmọ Jakọbu, ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fún un. +Jakọbu sọ fún Simeoni ati Lefi pé, “Irú ìyọnu wo ni ẹ kó mi sí yìí? Ẹ sọ mí di ọ̀tá gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ yìí, láàrin àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. Àwa nìyí, a kò pọ̀ jù báyìí lọ. Tí wọ́n bá kó ara wọn jọ sí mi, wọn óo run mí tilé-tilé.” +Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “Àwa kò lè gbà kí ó ṣe arabinrin wa bí aṣẹ́wó.” +Ṣekemu bá lọ sọ fún Hamori, baba rẹ̀, pé kí ó fẹ́ ọmọbinrin náà fún òun. +Jakọbu ti gbọ́ pé ó ti ba Dina, ọmọ rẹ̀ jẹ́, ṣugbọn àwọn ọmọ rẹ̀ wà pẹlu àwọn ẹran ninu pápá, Jakọbu kò sọ nǹkankan títí tí wọ́n fi dé. +Hamori baba Ṣekemu tọ Jakọbu wá láti bá a sọ̀rọ̀. +Nígbà tí àwọn ọmọ Jakọbu pada dé sílé, tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, inú bí wọn gidigidi nítorí bíbá tí Ṣekemu bá Dina lòpọ̀ pẹlu ipá yìí jẹ́ ìwà àbùkù gbáà ní Israẹli, irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò tọ́ sí ẹnikẹ́ni láti hù. +Ṣugbọn Hamori bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní, “Ọkàn Ṣekemu, ọmọ mi, fà sí arabinrin yín, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fún un kí ó fi ṣe aya. +Ẹ jẹ́ kí á jọ máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ ara wa, ẹ máa fi àwọn ọmọbinrin yín fún wa, kí àwa náà máa fi àwọn ọmọbinrin wa fún yín. +Wọ́n fi Ipá bá Dina Lòpọ̀. +Lẹ́yìn náà, Ọlọrun sọ fún Jakọbu pé, “Dìde, lọ sí Bẹtẹli kí o máa gbé ibẹ̀, kí o tẹ́ pẹpẹ kan fún Ọlọrun tí ó farahàn ọ́ nígbà tí ò ń sálọ fún Esau, arakunrin rẹ.” +Ọlọrun wí fún un pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ, ṣugbọn wọn kò ní pè ọ́ ní Jakọbu mọ́, Israẹli ni orúkọ rẹ yóo máa jẹ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe sọ ọ́ ní Israẹli. +Ọlọrun tún sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa bímọ lémọ, kí o sì pọ̀ sí i, ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati ọpọlọpọ ọba ni yóo ti ara rẹ jáde. +N óo fún ọ ní ilẹ̀ tí mo fún Abrahamu ati Isaaki, àwọn ọmọ rẹ ni yóo sì jogún rẹ̀.” +Ọlọrun bá gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti bá a sọ̀rọ̀. +Jakọbu gbé ọ̀wọ̀n òkúta kan nàró níbẹ̀, ó fi ohun mímu rúbọ lórí òkúta náà, ó ta òróró sórí rẹ̀, +Ó sì sọ ibẹ̀ ní Bẹtẹli. +Wọ́n kúrò ní Bẹtẹli, nígbà tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n dé Efurati ni ọmọ mú Rakẹli, ara sì ni ín gidigidi. +Bí ó ti ń rọbí lọ́wọ́, agbẹ̀bí tí ń gbẹ̀bí rẹ̀ ń dá a lọ́kàn le pé, “Má bẹ̀rù, ọkunrin ni o óo tún bí.” +Nígbà tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bọ́ lọ, kí ó tó kú, ó sọ ọmọ náà ní Benoni, ṣugbọn baba rẹ̀ sọ ọ́ ní Bẹnjamini. +Bẹ́ẹ̀ ni Rakẹli ṣe kú, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà Efurati, èyí nnì ni Bẹtilẹhẹmu. +Jakọbu bá sọ fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ ati àwọn alábàágbé rẹ̀, pé, “Ẹ kó gbogbo ère oriṣa tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín dànù, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín. +Jakọbu gbé ọ̀wọ̀n kan nàró lórí ibojì rẹ̀, òun ni wọ́n ń pè ní ọ̀wọ̀n ibojì Rakẹli, ó sì wà níbẹ̀ títí di òní. +Jakọbu tún bẹ̀rẹ̀ sí bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó pàgọ́ rẹ̀ sí òdìkejì ilé ìṣọ́ Ederi. +Nígbà tí Israẹli ń gbé ibẹ̀, Reubẹni bá Biliha, aya baba rẹ̀ lòpọ̀, Jakọbu sì gbọ́ nípa rẹ̀. +Àwọn ọmọ Jakọbu jẹ́ mejila. Àwọn tí Lea bí ni: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu. Lẹ́hìn rẹ̀ ni ó bí Simeoni, Lefi, Juda, Isakari ati Sebuluni. +Àwọn tí Rakẹli bí ni: Josẹfu ati Bẹnjamini. +Àwọn tí Biliha, iranṣẹbinrin Rakẹli bí ni: Dani ati Nafutali. +Àwọn tí Silipa, iranṣẹbinrin Lea bí ni: Gadi ati Aṣeri. Àwọn wọnyi ni àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún Jakọbu ní Padani-aramu. +Jakọbu pada sọ́dọ̀ Isaaki, baba rẹ̀, ní Mamure, ìlú yìí kan náà ni wọ́n ń pè ní Kiriati Ariba tabi Heburoni, níbi tí Abrahamu ati Isaaki gbé. +Isaaki jẹ́ ẹni ọgọsan-an (180) ọdún nígbà tí ó kú. +Ó dàgbà, ó darúgbó lọpọlọpọ kí ó tó kú. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Esau ati Jakọbu, sì sin ín. +Lẹ́yìn náà ẹ jẹ́ kí á lọ sí Bẹtẹli, kí n lè tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ fún Ọlọrun, ẹni tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú, tí ó sì wà pẹlu mi ní gbogbo ibi tí mo ti lọ.” +Gbogbo wọn bá dá àwọn ère oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn jọ fún Jakọbu, ati gbogbo yẹtí tí ó wà ní etí wọn, Jakọbu bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ lábẹ́ igi oaku tí ó wà ní Ṣekemu. +Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn. Jìnnìjìnnì láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sì dà bo gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká wọn, wọn kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu. +Jakọbu ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá wá sí Lusi, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí nnì ni Bẹtẹli. +Ó tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ, ó sì sọ ibẹ̀ ní Eli-Bẹtẹli, nítorí pé níbẹ̀ ni Ọlọrun ti farahàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arakunrin rẹ̀. +Níbẹ̀ ni Debora, olùtọ́jú Rebeka kú sí, wọ́n sì sin ín sí abẹ́ igi oaku kan ní ìhà gúsù Bẹtẹli, Jakọbu bá sọ ibẹ̀ ní Aloni-bakuti. +Ọlọrun tún fara han Jakọbu, nígbà tí ó jáde kúrò ní Padani-aramu, ó súre fún un. +Ọlọrun Súre fún Jakọbu ní Bẹtẹli. +Àkọsílẹ̀ ìran Esau, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu nìyí: +orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ ni, Elifasi, tí Ada bí, ati Reueli, tí Basemati bí. +Àwọn ọmọ Elifasi ni: Temani, Omari, Sefo, Gatamu ati Kenasi. +(Elifasi, ọmọ Esau ní obinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Timna, òun ni ó bí Amaleki fún un.) Àwọn ni àwọn ọmọ Ada, aya Esau. +Àwọn ọmọ Reueli ni Nahati, Sera, Ṣama, ati Misa. Àwọn ni àwọn ọmọ Basemati, aya Esau. +Àwọn ọmọ tí Oholibama, ọmọ Ana, ọmọ Sibeoni, aya Esau, bí fún un ni Jeuṣi, Jalamu ati Kora. +Àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ninu àwọn ọmọ Esau nìwọ̀nyí, Lára àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau, tí Ada bí fún un: Temani, Omari, Sefo, Kenasi. +Kora, Gatamu, ati Amaleki. Àwọn wọnyii jẹ́ ọmọ Ada, aya Esau. +Lára àwọn ọmọ Reueli, ọmọ Esau, àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ni: Nahati, Sera, Ṣama, ati Misa. Àwọn ni ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Reueli, ní ilẹ̀ Edomu, wọ́n sì jẹ́ ọmọ Basemati, aya Esau. +Lára àwọn ọmọ Oholibama, aya Esau: àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ni: Jeuṣi, Jalamu, ati Kora. Àwọn ni ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Oholibama, ọmọ Ana, aya Esau. +Wọ́n jẹ́ ọmọ Esau, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu, àwọn sì ni ìjòyè tí wọ́n ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣẹ̀. +Ninu àwọn ọmọbinrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ aya, ekinni ń jẹ́ Ada, ọmọ Eloni ará Hiti, ekeji ń jẹ́ Oholibama, ọmọ Ana tí baba rẹ̀ ń jẹ́ Sibeoni, ará Hifi. +Àwọn ọmọ Seiri ará Hori, tí ń gbé ilẹ̀ náà nìyí: àwọn ọmọ rẹ̀ ni: Lotani, Ṣobali, Sibeoni ati Ana, +Diṣoni, Eseri, ati Diṣani, àwọn ni ìjòyè ní ilẹ̀ Hori, wọ́n sì jẹ́ ọmọ Seiri ní ilẹ̀ Edomu. +Àwọn ọmọ Lotani ni Hori, ati Hemani, Timna ni arabinrin Lotani. +Àwọn ọmọ Ṣobali ni Alfani, Manahati, Ebali, Ṣefo ati Onamu. +Àwọn ọmọ Sibeoni ni Aya ati Ana. Ana yìí ni ó rí àwọn ìsun omi gbígbóná láàrin aginjù, níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Sibeoni, baba rẹ̀. +Àwọn ọmọ Ana ni, Diṣoni ati Oholibama. +Àwọn ọmọ Diṣoni ni Hemdani, Eṣibani, Itirani, ati Kerani. +Àwọn ọmọ Eseri ni: Bilihani, Saafani, ati Akani. +Àwọn ọmọ Diṣani ni: Usi ati Arani. +Àwọn ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ lára Hori nìwọ̀nyí: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, +Ẹkẹta ń jẹ́ Basemati ọmọ Iṣimaeli, arabinrin Nebaiotu. +Diṣoni, Eseri, ati Diṣani. Àwọn ìjòyè ilẹ̀ Hori, gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé ìdílé wọn ní ilẹ̀ Seiri. +Àwọn ọba tí wọ́n jẹ ní ilẹ̀ Edomu kí ó tó di pé ẹnikẹ́ni jọba ní ilẹ̀ Israẹli nìwọ̀nyí: +Bela, ọmọ Beori jọba ní Edomu, orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba. +Nígbà tí Bela kú, Jobabu, ọmọ Sera, ará Bosira gorí oyè. +Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu ti ilẹ̀ Temani, gorí oyè. +Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi, ọmọ Bedadi, tí ó ṣẹgun Midiani, ní ilẹ̀ Moabu gorí oyè, orúkọ ìlú tirẹ̀ ni Afiti. +Nígbà tí Hadadi kú, Samila ti Masireka gorí oyè. +Nígbà tí Samila kú, Ṣaulu ará Rehoboti lẹ́bàá odò Yufurate gorí oyè. +Nígbà tí Ṣaulu kú, Baali Hanani, ọmọ Akibori gorí oyè. +Nígbà tí Baali Hanani ọmọ Akibori kú, Hadadi gorí oyè, orúkọ ìlú tirẹ̀ ni Pau, orúkọ aya rẹ̀ ni Mehetabeli, ọmọ Matiredi, ọmọbinrin Mesahabu. +Ada bí Elifasi fún Esau, Basemati bí Reueli. +Orúkọ àwọn ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ lára Esau nìwọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn ati ìlú tí olukuluku ti jọba: Timna, Alfa, Jeteti, +Oholibama, Ela, Pinoni, +Kenasi, Temani, Mibisari, +Magidieli ati Iramu. Àwọn ni ìjòyè ní Edomu, gẹ́gẹ́ bí ìlú wọn ní ilẹ̀ ìní wọn, Esau tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu sì ni baba àwọn ará Edomu. +Oholibama bí Jeuṣi, Jalamu ati Kora. Àwọn ni ọmọ Esau, tí àwọn aya rẹ̀ bí fún un ní ilẹ̀ Kenaani. +Nígbà tí ó ṣe, Esau kó àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn mààlúù rẹ̀, àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ti kójọ ní ilẹ̀ Kenaani, ó kó kúrò ní ilẹ̀ Kenaani lọ́dọ̀ Jakọbu, arakunrin rẹ̀. +Ìdí ni pé ọrọ̀ wọn ti pọ̀ ju kí wọ́n jọ máa gbé pọ̀ lọ, ilẹ̀ tí wọ́n sì ti ń ṣe àtìpó kò gbà wọ́n mọ́, nítorí pé wọ́n ní ẹran ọ̀sìn tí ó pọ̀. +Bẹ́ẹ̀ ni Esau ṣe di ẹni tí ń gbé orí òkè Seiri. Esau kan náà ni ń jẹ́ Edomu. +Àkọsílẹ̀ ìran Esau, baba àwọn ará Edomu, tí ń gbé orí òkè Seiri nìyí: +Àwọn Ìran Esau. +Jakọbu ń gbé ilẹ̀ Kenaani, níbi tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe àtìpó. +Nígbà tí ó rọ́ àlá náà fún baba rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Baba rẹ̀ bá a wí, ó ní, “Irú àlá rándanràndan wo ni ò ń lá wọnyi? Ṣé èmi, ati ìyá rẹ, ati àwọn arakunrin rẹ yóo wá foríbalẹ̀ fún ọ ni?” +Àwọn arakunrin rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara rẹ̀, ṣugbọn baba rẹ̀ kò gbàgbé ọ̀rọ̀ náà, ó ń rò ó ní ọkàn rẹ̀. +Ní ọjọ́ kan àwọn arakunrin rẹ̀ ń da agbo aguntan baba wọn lẹ́bàá Ṣekemu, +Israẹli bá pe Josẹfu, ó ní, “Ǹjẹ́ Ṣekemu kọ́ ni àwọn arakunrin rẹ da ẹran lọ? Wò ó, wá kí n rán ọ sí wọn.” Josẹfu bá dáhùn pé, “Èmi nìyí.” +Israẹli sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́, lọ bá mi wo alaafia àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ati ti àwọn agbo ẹran wá, kí o sì tètè pada wá jíṣẹ́ fún mi.” Israẹli bá rán an láti àfonífojì Heburoni lọ sí Ṣekemu. +Níbi tí ó ti ń rìn kiri ninu pápá ni ọkunrin kan bá rí i, ó bi í pé, “Kí ni ò ń wá?” +Josẹfu dáhùn pé, “Àwọn arakunrin mi ni mò ń wá, jọ̀wọ́, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n da agbo ẹran wọn lọ?” +Ọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Wọ́n ti kúrò níhìn-ín, mo gbọ́ tí wọn ń bá ara wọn sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Dotani.’ ” Josẹfu bá tún lépa wọn lọ sí Dotani, ó sì bá wọn níbẹ̀. +Bí wọ́n ti rí i tí ó yọ lókèèrè, kí ó tilẹ̀ tó súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn láti pa á. +Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, alálàá ni ó ń bọ̀ yìí! +Àkọsílẹ̀ ìran Jakọbu nìyí: Josẹfu jẹ́ ọmọ ọdún mẹtadinlogun ó sì ń bá àwọn arakunrin rẹ̀ tọ́jú agbo ẹran ó wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Biliha ati àwọn ọmọ Silipa, àwọn aya baba rẹ̀. Josẹfu a sì máa sọ gbogbo àṣìṣe àwọn arakunrin rẹ̀ fún baba wọn. +Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí á wọ́ ọ sinu kòtò kan, kí á sọ pé ẹranko burúkú kan ni ó pa á jẹ, kí á wá wò ó bí àlá rẹ̀ yóo ṣe ṣẹ.” +Ṣugbọn nígbà tí Reubẹni gbọ́, ó gbà á kalẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó ní, “Ẹ má jẹ́ kí á pa á. +Ẹ má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, jíjù ni kí ẹ jù ú sinu kànga gbígbẹ láàrin aginjù yìí, ẹ má pa á lára rárá.” Ó fẹ́ fi ọgbọ́n yọ ọ́ lọ́wọ́ wọn, kí ó lè fi í ranṣẹ sí baba wọn pada. +Bí Josẹfu ti dé ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀, wọ́n fi ipá bọ́ ẹ̀wù aláràbarà rẹ̀ lọ́rùn rẹ̀, +wọ́n gbé e jù sinu kànga kan tí kò ní omi ninu. +Bí wọ́n ti jókòó tí wọ́n fẹ́ máa jẹun, ojú tí wọ́n gbé sókè, wọ́n rí ọ̀wọ́ àwọn ará Iṣimaeli kan, wọ́n ń bọ̀ láti Gileadi, wọ́n ń lọ sí Ijipti, àwọn ràkúnmí wọn ru turari, ìkunra olóòórùn dídùn ati òjíá. +Juda bá sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀, ó ní, “Anfaani wo ni yóo jẹ́ fún wa bí a bá pa arakunrin wa, tí a sì bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀? +Ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Iṣimaeli yìí. Ẹ má jẹ́ kí á pa á, nítorí arakunrin wa ni, ara kan náà ni wá.” Ọ̀rọ̀ náà sì dùn mọ́ àwọn arakunrin rẹ̀. +Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn oníṣòwò ará Midiani ń rékọjá lọ, wọ́n bá fa Josẹfu jáde láti inú kànga gbígbẹ náà, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Iṣimaeli ní ogún owó fadaka. Àwọn ará Iṣimaeli sì mú Josẹfu lọ sí Ijipti. +Nígbà tí Reubẹni pada dé ibi kànga gbígbẹ tí wọ́n ju Josẹfu sí, tí ó rí i pé kò sí níbẹ̀ mọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. +Israẹli fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù lọ, nítorí pé ó ti di arúgbó kí ó tó bí i, nítorí náà ó dá ẹ̀wù aláràbarà kan fún un. +Ó pada lọ bá àwọn arakunrin rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ọmọ náà kò sí níbẹ̀? Mo gbé! Ibo ni n óo yà sí?” +Wọ́n bá mú ọmọ ewúrẹ́ kan ninu agbo, wọ́n pa á, wọ́n sì ti ẹ̀wù Josẹfu bọ inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. +Wọ́n bá fi ẹ̀wù aláràbarà náà ranṣẹ sí baba wọn, wọ́n ní, “Ohun tí a rí nìyí. Wò ó wò, bóyá ẹ̀wù ọmọ rẹ ni, tabi òun kọ́.” +Jakọbu yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì wí pé, “Ẹ̀wù ọmọ mi ni, ẹranko burúkú kan ti pa á, dájúdájú, ẹranko náà ti fa Josẹfu ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” +Jakọbu bá fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọpọlọpọ ọjọ́. +Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin lọ láti tù ú ninu, ṣugbọn ó kọ̀, kò gba ìpẹ̀, ó ní, “Ninu ọ̀fọ̀ ni n óo wọ inú ibojì lọ bá ọmọ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni baba rẹ̀ sọkún rẹ̀. +Àwọn ará Midiani tí wọ́n ra Josẹfu tà á fún Pọtifari, ará Ijipti, ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè Farao. Pọtifari yìí ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba. +Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ yòókù rí i pé baba wọn fẹ́ràn Josẹfu ju àwọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọn kì í sì fi sùúrù bá a sọ̀rọ̀. +Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lá àlá kan, ó bá rọ́ àlá náà fún àwọn arakunrin rẹ̀, àlá yìí sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i. +Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́ àlá kan tí mo lá. +Èmi pẹlu yín, a wà ní oko ní ọjọ́ kan, à ń di ìtí ọkà, mo rí i tí ìtí ọkà tèmi wà lóòró, ó dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì yí i ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún un.” +Àwọn arakunrin rẹ̀ bá bi í pé, “Ṣé o rò pé ìwọ ni yóo jọba lórí wa ni? Tabi o óo máa pàṣẹ lé wa lórí?” Wọ́n sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i nítorí àlá tí ó lá ati nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀. +Ó tún lá àlá mìíràn, ó sì tún rọ́ ọ fún àwọn arakunrin rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbọ́, mo mà tún lá àlá mìíràn! Mo rí oòrùn, ati òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ mọkanla ní ojú àlá, gbogbo wọn foríbalẹ̀ fún mi.” +Josẹfu ati Àwọn Arakunrin Rẹ̀. +Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà ni Juda bá fi àwọn arakunrin rẹ̀ sílẹ̀, ó kó lọ sí ọ̀dọ̀ ará Adulamu kan tí wọn ń pè ní Hira. +Ohun tí Onani ń ṣe yìí kò dùn mọ́ Ọlọrun ninu, Ọlọrun bá pa òun náà. +Juda bá sọ fún Tamari opó ọmọ rẹ̀ pé, “Wá pada sí ilé baba rẹ kí o lọ máa ṣe opó níbẹ̀ títí tí Ṣela, ọmọ mi yóo fi dàgbà.” Ṣugbọn ọ̀rọ̀ tí Juda sọ yìí kò dé inú rẹ̀ nítorí ẹ̀rù ń bà á pé kí Ṣela náà má kú bí àwọn arakunrin rẹ̀, Tamari bá pada lọ sí ilé baba rẹ̀. +Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya Juda, tíí ṣe ọmọ Ṣua kú. Nígbà tí Juda ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, òun ati Hira ará Adulamu, ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá múra, wọ́n lọ sí Timna lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń rẹ́ irun aguntan Juda. +Àwọn kan lọ sọ fún Tamari pé baba ọkọ rẹ̀ ń lọ sí Timna láti rẹ́ irun aguntan rẹ̀. +Tamari bá bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò lára, ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ó wọ aṣọ tí ó dára, ó bá jókòó lẹ́nu bodè Enaimu tí ó wà lọ́nà Timna; nítorí ó mọ̀ pé Ṣela ti dàgbà, wọn kò sì ṣú òun lópó fún un. +Nígbà tí Juda rí Tamari tí ó fi aṣọ bojú, ó rò pé aṣẹ́wó ni. +Ó tọ̀ ọ́ lọ níbi tí ó jókòó sí lẹ́bàá ọ̀nà, ó ní, “Wá, jẹ́ kí n bá ọ lòpọ̀,” kò mọ̀ pé opó ọmọ òun ni. Tamari dá a lóhùn, ó ní: “Kí ni o óo fún mi tí mo bá gbà fún ọ?” +Juda dáhùn, ó ní, “N óo fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ kan ranṣẹ sí ọ láti inú agbo ẹran mi.” Tamari ní, “O níláti fi nǹkankan dógò títí tí o óo fi fi ọmọ ewúrẹ́ náà ranṣẹ.” +Juda bá bèèrè pé kí ni ó fẹ́ kí òun fi dógò.Ó dá a lóhùn, ó ní, “Èdìdì rẹ pẹlu okùn rẹ, ati ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ.” Juda bá kó wọn fún un, ó sì bá a lòpọ̀, Tamari sì lóyún. +Ó dìde, ó bá tirẹ̀ lọ, ó ṣí ìbòjú rẹ̀ kúrò, ó sì tún wọ aṣọ ọ̀fọ̀ rẹ̀. +Níbẹ̀ ni Juda ti rí ọmọbinrin ará Kenaani kan, tí baba rẹ̀ ń jẹ́ Ṣua, ó gbé e níyàwó, ó sì bá a lòpọ̀. +Juda fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Adulamu, sí Tamari, kí ó le bá a gba àwọn ohun tí ó fi dógò lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò bá a níbẹ̀ mọ́. +Ó bi àwọn ọkunrin kan, ará ìlú náà pé, “Níbo ni obinrin aṣẹ́wó tí ó máa ń jókòó ní gbangba lẹ́bàá ọ̀nà Enaimu yìí wà?”Wọ́n dáhùn pé, “Kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan ní àdúgbò yìí.” +Ọ̀rẹ́ Juda bá pada tọ̀ ọ́ lọ, ó ní òun kò rí i, ati pé àwọn ọkunrin tí wọ́n wà níbẹ̀ sọ pé kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan níbẹ̀. +Juda dá a lóhùn, ó ní, “Má wulẹ̀ wá a kiri mọ́, kí àwọn eniyan má baà máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. Jẹ́ kí ó ṣe àwọn nǹkan ọwọ́ rẹ̀ bí ó bá ti fẹ́, mo ṣá fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ tí mo ṣèlérí ranṣẹ, o kò rí i ni.” +Lẹ́yìn bí oṣù mẹta sí i, ẹnìkan wá sọ fún Juda pé, “Wò ó! Iṣẹ́ aṣẹ́wó ni Tamari, opó ọmọ rẹ ń ṣe, ó sì ti lóyún.”Juda bá dáhùn, ó ní, “Ẹ lọ mú un wá kí wọ́n dáná sun ún.” +Nígbà tí wọ́n mú un dé, ó ranṣẹ sí baba ọkọ rẹ̀, ó ní, “Ẹni tí ó ni àwọn nǹkan wọnyi ni ó fún mi lóyún. Jọ̀wọ́ yẹ̀ wọ́n wò, kí o mọ ẹni tí ó ni èdìdì yìí pẹlu okùn rẹ̀, ati ọ̀pá yìí.” +Juda yẹ̀ wọ́n wò, ó sì mọ̀ wọ́n, ó ní, “O ṣe olóòótọ́ jù mí lọ, èmi ni mo jẹ̀bi nítorí pé n kò ṣú ọ lópó fún Ṣela, ọmọ mi.” Kò sì bá a lòpọ̀ mọ́. +Nígbà tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ pé, wọ́n rí i pé ìbejì ni ó wà ninu rẹ̀. +Bí ó ti ń rọbí, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ náà yọ ọwọ́ jáde, ẹni tí ń bá a gbẹ̀bí bá so òwú pupa mọ́ ọn lọ́wọ́, ó ní “Èyí tí ó kọ́ jáde nìyí.” +Ṣugbọn bí ọmọ náà ti fa ọwọ́ rẹ̀ pada, arakunrin rẹ̀ bá jáde. Agbẹ̀bí náà bá wí pé, “Ṣé bí o ti fẹ́ rìn nìyí, ó hàn lára rẹ.” Ó bá sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi. +Ó lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, Juda sọ ọmọ náà ní Eri. +Láìpẹ́ arakunrin rẹ̀ náà wálẹ̀, pẹlu òwú pupa tí wọ́n so mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá sọ ọ́ ní Sera. +Ó tún lóyún, ó bí ọmọkunrin keji, ó sọ ọ́ ní Onani. +Ó tún lóyún mìíràn, ó tún bí ọkunrin bákan náà, ó bá sọ ọmọ náà ní Ṣela. Ìlú Kẹsibu ni ó wà nígbà tí ó bí ọmọ náà. +Juda fẹ́ aya fún Eri, àkọ́bí rẹ̀. Orúkọ obinrin náà ni Tamari. +Ìwà Eri burú tóbẹ́ẹ̀ tí Ọlọrun fi pa á. +Juda bá pe Onani, ó ní, “Ṣú iyawo arakunrin rẹ lópó kí o sì bá a lòpọ̀, kí ó lè bímọ fún arakunrin rẹ.” +Ṣugbọn Onani mọ̀ pé ọmọ tí opó náà bá bí kò ní jẹ́ ti òun, nítorí náà, nígbàkúùgbà tí ó bá ń bá opó yìí lòpọ̀, yóo sì da nǹkan ọkunrin rẹ̀ sílẹ̀, kí ó má baà bí ọmọ tí yóo rọ́pò arakunrin rẹ̀. +Juda ati Tamari. +Àwọn ará Iṣimaeli mú Josẹfu lọ sí Ijipti, wọ́n sì tà á fún Pọtifari ará Ijipti. Pọtifari yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè Farao, òun sì tún ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lojoojumọ ni ó ń rọ Josẹfu, sibẹsibẹ, Josẹfu kò gbà láti bá a lòpọ̀, tabi láti wà pẹlu rẹ̀. +Ṣugbọn ní ọjọ́ kan nígbà tí Josẹfu wọ inú ilé lọ láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni nílé ninu àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. +Obinrin yìí so mọ́ ọn lẹ́wù, ó ní, “Wá bá mi lòpọ̀.” Ṣugbọn Josẹfu bọ́rí kúrò ninu ẹ̀wù rẹ̀, ó sá jáde kúrò ninu ilé. +Nígbà tí ó rí i pé Josẹfu fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ati pé ó sá jáde kúrò ninu ilé, +ó pe àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀, ó sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ wo nǹkan, ọkọ mi ni ó mú Heberu yìí wá láti wá fi ẹ̀gbin lọ̀ wá. Ó wọlé wá bá mi láti bá mi lòpọ̀, ni mo bá pariwo. +Nígbà tí ó sì rí i pé mo pariwo, ó sá jáde, ó fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́.” +Obinrin náà bá fi ẹ̀wù rẹ̀ sọ́dọ̀ títí tí ọ̀gá rẹ̀ fi wọlé dé. +Nígbà tí ó dé, obinrin yìí sọ ohun kan náà fún un, ó ní, “Ẹrú ará Heberu tí o mú wá sí ààrin wa, ni ó déédé wọlé tọ̀ mí wá láti fi ẹ̀gbin lọ̀ mí, +ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé mo pariwo, ó ju ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́, ó sá jáde.” +Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí ẹrú rẹ ti ṣe sí mi nìyí” inú bí i gidigidi, +OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ninu ilé ọ̀gá rẹ̀, ará Ijipti, níbi tí ó ń gbé. Àwọn ohun tí ó ń ṣe sì ń yọrí sí rere. +ó sì sọ Josẹfu sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ibi tí wọn ń ti àwọn tí ọba bá sọ sí ẹ̀wọ̀n mọ́ ni wọ́n tì í mọ́. +Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ hàn sí i, ó jẹ́ kí ó bá ojurere alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà pàdé. +Alabojuto náà fi Josẹfu ṣe olùdarí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ẹ̀wọ̀n, ohunkohun tí Josẹfu bá sọ, ni wọ́n ń ṣe. +Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kì í fi nǹkan lé Josẹfu lọ́wọ́ kí ó tún bìkítà fún un mọ́, nítorí pé OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ohunkohun tí ó bá ṣe, OLUWA ń jẹ́ kí ó yọrí sí rere. +Ọ̀gá rẹ̀ ṣàkíyèsí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati pé OLUWA ń bukun ohun gbogbo tí ó bá dáwọ́lé. +Nítorí náà, ó rí ojurere Pọtifari. Pọtifari mú un sọ́dọ̀ pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún òun, ó fi ṣe alabojuto gbogbo ilé rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ rẹ̀. +Nígbà tí Pọtifari ti fi Josẹfu ṣe alabojuto ilé rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí bukun ìdílé Pọtifari, ará Ijipti náà, ati ohun gbogbo tí ó ní nítorí ti Josẹfu. +Nítorí náà, ó fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ Josẹfu níwọ̀n ìgbà tí ó wà pẹlu rẹ̀, kò sì bìkítà fún ohunkohun mọ́, àfi oúnjẹ tí ó ń jẹ.Josẹfu ṣígbọnlẹ̀, ó sì lẹ́wà. +Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Josẹfu wu aya ọ̀gá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ ọ́ pé kí ó wá bá òun lòpọ̀. +Ṣugbọn Josẹfu kọ̀, ó wí fún un pé, “Wò ó, níwọ̀n ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ ọ̀gá mi, kò bìkítà fún ohunkohun ninu ilé yìí, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ mi. +Kò sí ohun tí ó fi jù mí lọ ninu ilé yìí, kò sì sí ohun tí kò fi lé mi lọ́wọ́, àfi ìwọ nìkan, nítorí pé aya rẹ̀ ni ọ́. Ǹjẹ́ ó tọ́ sí mi láti ṣe irú ohun burúkú yìí kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun?” +Josẹfu ati Aya Pọtifari. +Nígbà tí ó yá, Adamu bá Efa, aya rẹ̀, lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní, “Pẹlu ìrànlọ́wọ́ OLUWA, mo ní ọmọkunrin kan,” ó sọ ọmọ náà ní Kaini. +OLUWA bá bi í pé “Kí ni o dánwò yìí? Láti inú ilẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ ti ń kígbe pè mí. +Wò ó! mo fi ọ́ gégùn-ún lórí ilẹ̀ tí ó mu ẹ̀jẹ̀ arakunrin rẹ tí o pa. +Láti òní lọ, nígbà tí o bá dá oko, ilẹ̀ kò ní fi gbogbo agbára rẹ̀ so èso fún ọ mọ́, ìsáǹsá ati alárìnká ni o óo sì jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.” +Kaini dá OLUWA lóhùn, ó ní, “Ìjìyà yìí ti pọ̀jù fún mi. +O lé mi kúrò lórí ilẹ̀, ati kúrò níwájú rẹ, n óo sì di ìsáǹsá ati alárìnká lórí ilẹ̀ ayé, nígbà tí ó bá yá, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi ni yóo pa mí.” +Ṣugbọn OLUWA dáhùn, ó ní, “Rárá o! ẹnikẹ́ni tí ó bá pa Kaini, a óo gbẹ̀san lára rẹ̀ nígbà meje.” Nítorí náà OLUWA fi àmì sí ara Kaini kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí i má baà pa á. +Kaini bá kúrò níwájú OLUWA, ó lọ ń gbé ìlú tí ń jẹ́ Nodu. Ó wà ní apá ìlà oòrùn ọgbà Edẹni. +Kaini bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí Enọku. Kaini lọ tẹ ìlú kan dó, ó sọ ìlú náà ní Enọku, tí í ṣe orúkọ ọmọ rẹ̀. +Enọku bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Iradi. Iradi bí Mehujaeli, Mehujaeli bí Metuṣaeli, Metuṣaeli bí Lamẹki. +Lamẹki fẹ́ iyawo meji, ọ̀kan ń jẹ́ Ada, ekeji ń jẹ́ Sila. +Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkunrin mìíràn, ó sọ ọ́ ní Abeli. Iṣẹ́ darandaran ni Abeli ń ṣe, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀. +Ada ni ó bí Jabali, tíí ṣe baba ńlá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn. +Orúkọ arakunrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba ńlá gbogbo àwọn tí wọn ń lu hapu ati àwọn tí wọn ń fọn fèrè. +Sila bí Tubali Kaini. Tubali Kaini yìí ni baba ńlá gbogbo àwọn alágbẹ̀dẹ tí ń rọ ohun èlò irin, ati idẹ. Arabinrin Tubali Kaini ni Naama. +Nígbà tí ó yá Lamẹki pe àwọn aya rẹ̀, ó ní:“Ada ati Sila, ẹ tẹ́tí sílẹ̀,ẹ̀yin aya mi, ẹ gbọ́ mi ní àgbọ́yé:Mo pa ọkunrin kan nítorí pé ó pa mí lára,mo gba ẹ̀mí eniyan nítorí pé ó ṣá mi lọ́gbẹ́. +Bí ẹ̀san ti Kaini bá jẹ́ ẹ̀mí eniyan meje,ẹ̀san ti Lamẹki gbọdọ̀ jẹ́ aadọrin ẹ̀mí ó lé meje.” +Adamu tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọ́ ní Seti, ó ní: “Ọlọrun tún fún mi ní ọmọ mìíràn dípò Abeli tí Kaini pa.” +Seti bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Enọṣi. Nígbà náà ni àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn ní orúkọ mímọ́ OLUWA. +Nígbà tí ó yá, Kaini mú ninu èso oko rẹ̀, ó fi rúbọ sí OLUWA. +Abeli náà mú àkọ́bí ọ̀kan ninu àwọn aguntan rẹ̀, ó pa á, ó sì fi ibi tí ó lọ́ràá, tí ó dára jùlọ lára rẹ̀ rúbọ sí OLUWA. Inú OLUWA dùn sí Abeli, ó sì gba ẹbọ rẹ̀, +ṣugbọn inú Ọlọrun kò dùn sí Kaini, kò sì gba ẹbọ rẹ̀. Inú bí Kaini, ó sì fa ojú ro. +OLUWA bá bi Kaini, ó ní, “Kí ló dé tí ò ń bínú, tí o sì fa ojú ro? +Bó bá jẹ́ pé o ṣe rere ni, ara rẹ ìbá yá gágá, ẹbọ rẹ yóo sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ṣugbọn nítorí pé ibi ni o ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ ba dè ọ́ lẹ́nu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ jọba lé ọ lórí ṣugbọn tìrẹ ni láti ṣẹgun rẹ̀.” +Nígbà tí ó yá, Kaini pe Abeli lọ sinu oko. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, Kaini dìde sí Abeli àbúrò rẹ̀, ó sì lù ú pa. +OLUWA bá pe Kaini, ó bi í pé, “Níbo ni Abeli, àbúrò rẹ wà?” Ó dáhùn, ó ní, “N kò mọ̀. Ṣé èmi wá jẹ́ bí olùṣọ́ àbúrò mi ni?” +Kaini ati Abeli. +Ní àkókò kan, agbọ́tí Farao, ọba Ijipti, ati olórí alásè rẹ̀ ṣẹ ọba. +Ìtàkùn náà ní ẹ̀ka mẹta, bí ewé rẹ̀ ti yọ, lẹsẹkẹsẹ, ni ó tanná, ó so, èso rẹ̀ sì pọ́n. +Ife Farao wà ní ọwọ́ mi, mo bá mú èso àjàrà náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí fún un sinu ife Farao, mo sì gbé ife náà lé Farao lọ́wọ́.” +Josẹfu bá sọ fún un pé, “Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: àwọn ẹ̀ka mẹta tí o rí dúró fún ọjọ́ mẹta. +Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta Farao yóo yọ ọ́ jáde, yóo dáríjì ọ́, yóo sì fi ọ́ sí ipò rẹ pada, o óo sì tún máa gbé ọtí fún Farao bíi ti àtẹ̀yìnwá. +Ṣugbọn ṣá o, ranti mi nígbà tí ó bá dára fún ọ, jọ̀wọ́, ṣe mí lóore kan, ròyìn mi fún Farao, kí Farao sì yọ mí kúrò ninu àhámọ́ yìí. +Nítorí pé jíjí ni wọ́n jí mi gbé kúrò ní ilẹ̀ Heberu, ati pé níhìn-ín gan-an, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ tí wọ́n fi gbé mi jù sẹ́wọ̀n yìí.” +Alásè rí i pé ìtumọ̀ rẹ̀ dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi náà lá àlá kan, mo ru agbọ̀n àkàrà mẹta lórí, lójú àlá. +Mo rí i pé oríṣìíríṣìí oúnjẹ Farao ni ó wà ninu agbọ̀n tí ó wà ní òkè patapata, mo bá tún rí i tí àwọn ẹyẹ bẹ̀rẹ̀ sí jẹ àwọn oúnjẹ yìí ní orí mi.” +Josẹfu dáhùn, ó ní, “Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: àwọn agbọ̀n mẹta náà dúró fún ọjọ́ mẹta. +Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, Farao ọba yóo yọ ọ́ jáde níhìn-ín, yóo bẹ́ ọ lórí, yóo gbé ọ kọ́ igi, àwọn ẹyẹ yóo sì jẹ ẹran ara rẹ.” +Inú bí Farao sí àwọn iranṣẹ rẹ̀ mejeeji yìí, +Ní ọjọ́ kẹta tíí ṣe ọjọ́ ìbí Farao, ọba se àsè ńlá fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì mú agbọ́tí rẹ̀ ati alásè rẹ̀ jáde sí ààrin àwọn iranṣẹ rẹ̀. +Ó dá agbọ́tí pada sí ipò rẹ̀ láti máa gbé ọtí fún un, +ṣugbọn ó pàṣẹ kí wọ́n lọ so olórí alásè kọ́ igi, gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti túmọ̀ àlá wọn fún wọn. +Ṣugbọn olórí agbọ́tí kò ranti Josẹfu mọ, ó gbàgbé rẹ̀ patapata. +ó sì jù wọ́n sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n tí Josẹfu wà. +Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fi wọ́n sábẹ́ àkóso Josẹfu, wọ́n sì wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fún ìgbà díẹ̀. +Ní òru ọjọ́ kan, agbọ́tí ọba ati olórí alásè náà lá àlá kan, àlá tí olukuluku lá sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀. +Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ tí Josẹfu rí wọn, ó rí i pé ọkàn wọn dàrú. +Ó bá bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ojú yín fi rẹ̀wẹ̀sì lónìí?” +Wọ́n dá a lóhùn pé, “A lá àlá kan ni, a kò sì rí ẹni bá wa túmọ̀ rẹ̀.”Josẹfu dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣebí Ọlọrun ni ó ni ìtumọ̀ àlá? Ẹ rọ́ àlá náà fún mi.” +Agbọ́tí bá rọ́ àlá tirẹ̀ fún Josẹfu, ó ní, “Mo rí ìtàkùn àjàrà kan lójú àlá. +Josẹfu Túmọ̀ Àlá Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Meji. +Lẹ́yìn ọdún meji gbáko, Farao náà wá lá àlá pé òun dúró létí odò Naili. +Nígbà tí inú fi bí ọba sí àwa iranṣẹ rẹ̀ meji, tí ọba sì gbé èmi ati alásè jù sẹ́wọ̀n ní ilé olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin, +àwa mejeeji lá àlá ní òru ọjọ́ kan náà, olukuluku àlá tí a lá ni ó sì ní ìtumọ̀. +Ọdọmọkunrin Heberu kan wà níbẹ̀ pẹlu wa, ó jẹ́ iranṣẹ olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin, nígbà tí a rọ́ àlá wa fún un, ó túmọ̀ wọn fún wa. Bí olukuluku wa ti lá àlá tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ó túmọ̀ wọn. +Gẹ́gẹ́ bí ó ti túmọ̀ àlá wa, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó sì rí. Ọba dá mi pada sí ààyè mi, ó sì pàṣẹ kí wọ́n so alásè kọ́.” +Farao bá ranṣẹ lọ pe Josẹfu, wọ́n sì mú un jáde kúrò ninu ẹ̀wọ̀n kíá. Lẹ́yìn tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá siwaju Farao. +Farao sọ fún un pé, “Mo lá àlá kan, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè túmọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá sọ fún mi pé, bí o bá gbọ́ àlá, o óo lè túmọ̀ rẹ̀.” +Josẹfu dá Farao lóhùn, ó ní, “Kò sí ní ìkáwọ́ mi, Ọlọrun ni yóo fún kabiyesi ní ìdáhùn rere.” +Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó, lójú àlá, bí mo ti dúró létí bèbè odò Naili, +mo rí i tí àwọn mààlúù meje kan tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀, tí ara wọn sì ń dán, ti inú odò náà jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko létí odò. +Àwọn mààlúù meje mìíràn tún jáde láti inú odò náà, gbogbo wọn rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, n kò rí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. +Ó rí àwọn mààlúù meje kan tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀, tí ara wọ́n sì ń dán, wọ́n ti inú odò náà jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko létí odò. +Àwọn mààlúù tí wọ́n rù wọnyi gbé àwọn tí wọ́n sanra mì. +Nígbà tí wọ́n gbé wọn mì tán, eniyan kò lè mọ̀ rárá pé wọ́n jẹ ohunkohun, nítorí pé wọ́n tún rù hangangan bákan náà ni. Mo bá tají. +Mo tún lá àlá lẹẹkeji, mo rí ṣiiri ọkà meje lórí igi ọkà kan, wọ́n tóbi, wọ́n sì yọmọ. +Mo tún rí i tí ṣiiri ọkà meje mìíràn yọ lẹ́yìn wọn, wọ́n tínínrín, wọn kò sì ní ọmọ ninu rárá, nítorí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ wọn lára. +Àwọn ṣiiri ọkà tí kò níláárí wọnyi gbé àwọn tí wọ́n dára mì. Mo rọ́ àwọn àlá mi fún àwọn adáhunṣe, ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó lè túmọ̀ wọn fún mi.” +Josẹfu sọ fún Farao, ó ní, “Ọ̀kan náà ni àlá mejeeji, Ọlọrun fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi ni. +Àwọn mààlúù rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀ meje nnì ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí wọ́n yọmọ dúró fún ọdún meje. Ọ̀kan náà ni àwọn àlá mejeeji. +Àwọn mààlúù meje tí wọ́n rù, tí wọ́n sì rí jàpàlà jàpàlà tí wọ́n jáde lẹ́yìn àwọn ti àkọ́kọ́, ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí kò yọmọ, tí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ lára, àwọn náà dúró fún ìyàn ọdún meje. +Bí ọ̀rọ̀ ti rí gan-an ni mo sọ fún kabiyesi yìí, Ọlọrun ti fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi. +Ọdún meje kan ń bọ̀ tí oúnjẹ yóo pọ̀ yanturu ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, +Rírí tí yóo tún rí, ó rí àwọn mààlúù meje mìíràn, wọ́n tún ti inú odò náà jáde wá, àwọn wọnyi rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, wọ́n dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn meje ti àkọ́kọ́. +ṣugbọn lẹ́yìn náà ìyàn yóo mú fún ọdún meje, ìyàn náà yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọdún meje tí oúnjẹ pọ̀ yóo di ìgbàgbé ní ilẹ̀ Ijipti, ìyàn náà yóo run ilẹ̀ yìí. +Ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀ pé oúnjẹ ti fi ìgbà kan pọ̀ rí, nítorí ìyàn ńlá tí yóo tẹ̀lé e yóo burú jáì. +Ìdí tí àlá kabiyesi náà fi jẹ́ meji ni láti fihàn pé Ọlọrun ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, láìpẹ́, Ọlọrun yóo mú un ṣẹ. +“Bí ọ̀rọ̀ ti rí yìí, ó yẹ kí kabiyesi yan ọkunrin kan tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye, kí ó fi ṣe olórí ní ilẹ̀ Ijipti. +Kí kabiyesi yan àwọn alabojuto ní ilẹ̀ náà kí wọ́n kó ìdámárùn-ún ìkórè ilẹ̀ Ijipti jọ láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ yóo fi wà. +Kí wọ́n kó gbogbo oúnjẹ wọnyi jọ ninu ọdún tí oúnjẹ yóo pọ̀, kí wọ́n sì kó wọn pamọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá, pẹlu àṣẹ kabiyesi, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ọ. +Oúnjẹ yìí ni àwọn eniyan yóo máa jẹ láàrin ọdún meje tí ìyàn yóo mú ní ilẹ̀ Ijipti, kí ilẹ̀ náà má baà parun ní àkókò ìyàn náà.” +Ìmọ̀ràn náà dára lójú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀. +Ó bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ a lè rí irú ọkunrin yìí, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀?” +Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìwọ ni Ọlọrun fi gbogbo nǹkan yìí hàn, kò sí ẹni tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye bíi rẹ. +Àwọn meje tí wọ́n rù hangangan náà ki àwọn meje tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀ mọ́lẹ̀, wọ́n sì gbé wọn mì, Farao bá tají. +Ìwọ ni yóo máa ṣe olórí ilé mi, gbogbo àṣẹ tí o bá sì pa ni àwọn eniyan mi yóo tẹ̀lé, kìkì pé mo jẹ́ ọba nìkan ni n óo fi jù ọ́ lọ.” +Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó! Mo fi ọ́ ṣe alákòóso ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.” +Farao bá bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó fi bọ Josẹfu lọ́wọ́, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun olówó iyebíye, ó sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. +Farao ní kí Josẹfu gun ọkọ̀ ogun rẹ̀ keji gẹ́gẹ́ bí igbákejì ọba, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí hó níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà!” Bẹ́ẹ̀ ni Farao ṣe fi Josẹfu ṣe olórí, ní ilẹ̀ Ijipti. +Farao tún sọ fún un pé, “Èmi ni Farao, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun ní ilẹ̀ Ijipti láìjẹ́ pé o fọwọ́ sí i.” +Lẹ́yìn náà ó sọ Josẹfu ní orúkọ Ijipti kan, orúkọ náà ni Safenati Panea, ó sì fi Asenati, ọmọ Pọtifera, fún un láti fi ṣe aya. Pọtifera yìí jẹ́ babalóòṣà oriṣa Oni, ní ìlú Heliopolisi. Josẹfu sì lọ káàkiri ilẹ̀ Ijipti. +Josẹfu jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lábẹ́ Farao, ọba Ijipti. A máa lọ láti ààfin ọba Farao káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ijipti. +Láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà, ilẹ̀ so èso lọpọlọpọ. +Josẹfu bẹ̀rẹ̀ sí kó oúnjẹ jọ fún ọdún meje tí oúnjẹ fi pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ Ijipti, ó ń pa wọ́n mọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n bá rí kójọ ní agbègbè ìlú ńlá kọ̀ọ̀kan, Josẹfu a kó o pamọ́ sinu ìlú ńlá náà. +Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe kó ọkà jọ jantirẹrẹ bíi yanrìn etí òkun. Nígbà tó yá, òun gan-an kò mọ ìwọ̀n ọkà náà mọ́, nítorí pé ó ti pọ̀ kọjá wíwọ̀n. +Ó tún sùn, ó sì lá àlá mìíràn, rírí tí yóo tún rí, ó rí ṣiiri ọkà meje lórí ẹyọ igi ọkà kan, wọ́n tóbi, wọ́n sì yọmọ. +Asenati, ọmọ Pọtifera, babalóòṣà Oni, bí ọkunrin meji fún Josẹfu kí ìyàn tó bẹ̀rẹ̀. +Josẹfu sọ ọmọ rẹ̀ kinni ní Manase, ó ní, “Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìnira mi ati ilé baba mi.” +Ó sọ ọmọ keji ní Efuraimu, ó ní, “Ọlọrun ti mú mi bí sí i ní ilẹ̀ tí mo ti rí ìpọ́njú.” +Nígbà tí ó yá, ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà ní Ijipti dópin. +Ọdún meje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti wí, ìyàn mú ní ilẹ̀ gbogbo, ṣugbọn oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. +Nígbà tí oúnjẹ kò sí mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, àwọn eniyan náà kígbe tọ Farao lọ fún oúnjẹ. Farao sọ fún gbogbo wọn pé, “Ẹ tọ Josẹfu lọ, ohunkohun tí ó bá wí fun yín ni kí ẹ ṣe.” +Nígbà tí ìyàn náà tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, Josẹfu ṣí àwọn àká tí wọ́n kó oúnjẹ pamọ́ sí, ó ń ta oúnjẹ fún àwọn ará Ijipti, nítorí ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ náà. +Gbogbo ayé ni ó sì ń wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní Ijipti tí wọ́n wá ra oúnjẹ, nítorí pé ìyàn náà mú gidigidi ní gbogbo ayé. +Ó sì tún rí i tí ṣiiri ọkà meje mìíràn yọ lẹ́yìn wọn, wọ́n tínínrín, wọn kò sì ní ọmọ ninu rárá, nítorí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ wọn lára. +Àwọn ṣiiri ọkà tínínrín meje náà gbé àwọn meje tí wọ́n yọmọ mì. Farao bá tún tají, ó sì tún rí i pé àlá ni òun ń lá. +Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ìdààmú bá Farao, ó bá ranṣẹ lọ pe gbogbo àwọn adáhunṣe ati àwọn amòye ilẹ̀ Ijipti, ó rọ́ àlá náà fún wọn, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ó lè túmọ̀ rẹ̀ fún un. +Nígbà náà ni agbọ́tí sọ fún Farao pé, “Mo ranti ẹ̀ṣẹ̀ mi lónìí. +Josẹfu Túmọ̀ Àlá Ọba. +Nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ijipti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Kí ni ẹ̀ ń wo ara yín fún? +Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o, oluwa mi, oúnjẹ ni àwa iranṣẹ rẹ wá rà. +Ọmọ baba kan náà ni gbogbo wa, olóòótọ́ eniyan sì ni wá, a kì í ṣe amí.” +Josẹfu tún sọ fún wọn pé, “N kò gbà, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.” +Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Ọkunrin mejila ni àwa iranṣẹ rẹ, tí a jẹ́ ọmọ baba kan náà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa wà lọ́dọ̀ baba wa nílé, ọ̀kan yòókù ti kú.” +Ṣugbọn Josẹfu tẹnumọ́ ọn pé, “Bí mo ti wí gan-an ni ọ̀rọ̀ rí, amí ni yín. +Ohun tí n óo fi mọ̀ pé olóòótọ́ ni yín nìyí: mo fi orúkọ Farao búra, ẹ kò ní jáde níhìn-ín àfi bí ẹ bá mú àbíkẹ́yìn baba yín wá. +Ẹ rán ọ̀kan ninu yín kí ó lọ mú àbíkẹ́yìn yín wá, ẹ̀yin yòókù ẹ óo wà ninu ẹ̀wọ̀n títí a óo fi mọ̀ bóyá òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mo tún fi orúkọ Farao búra, amí ni yín.” +Ó bá da gbogbo wọn sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọjọ́ mẹta. +Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta, Josẹfu wí fún wọn pé, “Mo bẹ̀rù Ọlọrun, nítorí náà, bí ẹ bá ṣe ohun tí n óo sọ fun yín yìí, n óo dá ẹ̀mí yín sí. +Tí ó bá jẹ́ pé olóòótọ́ eniyan ni yín, kí ọ̀kan ninu yín wà ninu ẹ̀wọ̀n, kí ẹ̀yin yòókù ru ọkà lọ sí ilé fún ìdílé yín tí ebi ń pa, +Ẹ wò ó, mo gbọ́ pé ọkà wà ní Ijipti, ẹ lọ ra ọkà wá níbẹ̀ kí ebi má baà pa wá kú.” +kí ẹ wá mú àbíkẹ́yìn yín tí ẹ̀ ń wí wá, kí n rí i, kí á lè mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, ẹ óo sì wà láàyè.”Wọ́n bá gbà bẹ́ẹ̀. +Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ̀rọ̀ pé, “Dájúdájú, a jẹ̀bi arakunrin wa, nítorí pé a rí ìdààmú ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá, ṣugbọn a kò dá a lóhùn, ohun tí ó fà á nìyí tí ìdààmú yìí fi dé bá wa.” +Reubẹni bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Mo sọ fun yín àbí n kò sọ, pé kí ẹ má fi ohunkohun ṣe ọmọ náà? Ṣugbọn ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́, òun nìyí nisinsinyii, ẹ̀san ni ó dé yìí.” +Wọn kò mọ̀ pé Josẹfu gbọ́ gbogbo ohun tí wọn ń wí, nítorí pé ògbufọ̀ ni wọ́n fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀. +Josẹfu bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ sọkún, ó tún pada wá láti bá wọn sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni láàrin wọn, ó dè é lókùn. +Josẹfu pàṣẹ pé kí wọ́n di ọkà sinu àpò olukuluku wọn, kí ó kún, kí wọ́n dá owó olukuluku pada sinu àpò rẹ̀, kí wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọn yóo jẹ lójú ọ̀nà. Wọ́n ṣe fún wọn bí Josẹfu ti wí. +Wọ́n di ẹrù wọn ru àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì gbọ̀nà ilé. +Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn yóo sùn lálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀kan ninu wọn tú àpò rẹ̀ láti fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní oúnjẹ, ó bá rí owó rẹ̀ tí wọ́n dì sí ẹnu àpò rẹ̀. +Ó wí fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé, “Wọ́n dá owó mi pada, òun nìyí lẹ́nu àpò mi yìí.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n ń wo ara wọn lójú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n, wọ́n ní, “Irú kí ni Ọlọrun ṣe sí wa yìí?” +Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n kó gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n rò fún un, wọ́n ní, +Àwọn arakunrin Josẹfu mẹ́wàá bá lọ sí Ijipti, wọ́n lọ ra ọkà. +“Ọkunrin tíí ṣe alákòóso ilẹ̀ náà sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó ṣebí a wá ṣe amí ilẹ̀ náà ni. +Ṣugbọn a wí fún un pé, ‘Olóòótọ́ ni wá, a kì í ṣe eniyankeniyan, ati pé a kì í ṣe amí rárá. +Ọkunrin mejila ni àwa tí a jẹ́ ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ninu wa ti kú, èyí tí ó kéré jù sì wà lọ́dọ̀ baba wa ní ilẹ̀ Kenaani.’ +Ọkunrin náà bá dáhùn pé, ohun tí yóo jẹ́ kí òun mọ̀ pé olóòótọ́ eniyan ni wá ni pé kí á fi ọ̀kan ninu wa sílẹ̀ lọ́dọ̀ òun, kí á gbé ọkà lọ sílé, kí ebi má baà pa ìdílé wa. +Kí á mú àbúrò wa patapata wá fún òun, nígbà náà ni òun yóo tó mọ̀ pé a kì í ṣe amí, ati pé olóòótọ́ eniyan ni wá, òun óo sì dá arakunrin wa pada fún wa, a óo sì ní anfaani láti máa ṣòwò ní ilẹ̀ Kenaani.” +Bí wọ́n ti tú àpò wọn, olukuluku bá owó rẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀. Nígbà tí àwọn ati baba wọn rí èyí, àyà wọn já. +Jakọbu baba wọn bá sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ ti jẹ́ kí n ṣòfò àwọn ọmọ mi: Josẹfu ti kú, Simeoni kò sí mọ́, ẹ tún fẹ́ mú Bẹnjamini lọ. Èmi nìkan ni gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ sí tán!” +Reubẹni bá wí fún baba rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi mejeeji, bí n kò bá mú Bẹnjamini pada wá fún ọ. Fi lé mi lọ́wọ́, n óo sì mú un pada wá fún ọ.” +Ṣugbọn Jakọbu dáhùn, ó ní, “Ọmọ tèmi kò ní bá yín lọ, nítorí pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ni ó kù. Bí ohunkohun bá ṣẹlẹ̀ sí i ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, mo ti darúgbó, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo rán mi sọ́run.” +Ṣugbọn Jakọbu kò jẹ́ kí Bẹnjamini, arakunrin Josẹfu bá àwọn arakunrin rẹ̀ lọ, nítorí ẹ̀rù ń bà á kí nǹkankan má tún lọ ṣẹlẹ̀ sí òun náà. +Àwọn ọmọ Israẹli lọ ra ọkà pẹlu àwọn mìíràn tí wọ́n wá ra ọkà, nítorí kò sí ibi tí ìyàn náà kò dé ní ilẹ̀ Kenaani. +Ní gbogbo àkókò yìí, Josẹfu ni gomina ilẹ̀ Ijipti, òun ni ó ń ta ọkà fún àwọn eniyan láti gbogbo orílẹ̀-èdè. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ dé, wọ́n kí i, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. +Josẹfu rí àwọn arakunrin rẹ̀, ó sì mọ̀ wọ́n, ṣugbọn ó bá wọn sọ̀rọ̀ pẹlu ohùn líle bí ẹni pé kò mọ̀ wọ́n rí, ó ní, “Níbo ni ẹ ti wá?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni, oúnjẹ ni a wá rà.” +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Josẹfu mọ̀ dájú pé àwọn arakunrin òun ni wọ́n, wọn kò mọ̀ ọ́n. +Josẹfu wá ranti àlá rẹ̀ tí ó lá nípa wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Amí ni yín, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.” +Àwọn Arakunrin Josẹfu Lọ Ra Ọkà ní Ijipti. +Ìyàn tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani ṣá túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni. +nítorí pé bí a kò bá fi ìrìn àjò yìí falẹ̀ ni, à bá ti lọ, à bá sì ti dé, bí ẹẹmeji.” +Israẹli, baba wọn bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dára, báyìí ni kí ẹ ṣe, ẹ dì ninu àwọn èso tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ yìí sinu àpò yín, kí ẹ gbé e lọ fún ọkunrin náà. Ẹ mú ìpara díẹ̀, oyin díẹ̀, turari díẹ̀ ati òjíá díẹ̀, ẹ mú èso pistakio ati èso alimọndi pẹlu. +Ìlọ́po meji owó ọjà tí ẹ óo rà ni kí ẹ mú lọ́wọ́, ẹ mú owó tí ó wà lẹ́nu àpò yín níjelòó lọ́wọ́ pẹlu, bóyá wọ́n gbàgbé ni. +Ẹ mú arakunrin yín náà lọ́wọ́, kí ẹ sì tọ ọkunrin náà lọ. +Kí Ọlọrun Olodumare jẹ́ kí ọkunrin náà ṣàánú yín, kí ó sì dá arakunrin yín kan yòókù ati Bẹnjamini pada. Bí mo bá tilẹ̀ wá ṣòfò àwọn ọmọ mi nígbà náà, n óo gbà pé mo ṣòfò wọn.” +Àwọn ọkunrin náà bá gbé ẹ̀bùn náà, wọ́n sì mú ìlọ́po meji owó tí wọ́n nílò, ati Bẹnjamini, wọ́n lọ siwaju Josẹfu ní Ijipti. +Nígbà tí Josẹfu rí Bẹnjamini pẹlu wọn, ó sọ fún alabojuto ilé rẹ̀, ó ní, “Mú àwọn ọkunrin wọnyi wọlé, pa ẹran kan kí o sì sè é, nítorí wọn yóo bá mi jẹun lọ́sàn-án yìí.” +Ọkunrin náà ṣe bí Josẹfu ti pàṣẹ fún un, ó sì mú àwọn ọkunrin náà wọ ilé Josẹfu lọ. +Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí bà wọ́n nígbà tí Josẹfu mú wọn wọ ilé rẹ̀, wọ́n ń wí fún ara wọn pé, “Nítorí owó tí wọ́n fi sí ẹnu àpò wa níjelòó ni wọ́n fi kó wa wọlé, kí ó lè rí ẹ̀sùn kà sí wa lẹ́sẹ̀, kí ó lè fi wá ṣe ẹrú, kí ó sì kó àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.” +Wọ́n bá tọ alabojuto ilé Josẹfu lọ lẹ́nu ọ̀nà, +Nígbà tí wọ́n jẹ ọkà tí wọ́n rà ní Ijipti tán, baba wọn pè wọ́n, ó ní, “Ẹ tún wá lọ ra oúnjẹ díẹ̀ sí i.” +wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ oluwa mi, a ti kọ́kọ́ wá ra oúnjẹ níhìn-ín nígbà kan. +Nígbà tí à ń pada lọ tí a dé ibi tí a fẹ́ sùn, a tú àpò wa, olukuluku wa bá owó tirẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀, kò sí ti ẹni tí ó dín rárá, a mú owó náà lọ́wọ́ báyìí. +A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ pẹlu láti ra oúnjẹ. A kò mọ ẹni tí ó dá owó wa pada sinu àpò wa.” +Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ fọkàn yín balẹ̀, ẹ má bẹ̀rù, ó níláti jẹ́ pé Ọlọrun yín ati ti baba yín ni ó fi owó náà sinu àpò yín fun yín, mo gba owó lọ́wọ́ yín.” Ó bá mú Simeoni jáde sí wọn. +Ọkunrin náà mú wọn wọ inú ilé Josẹfu, ó fún wọn ní omi, wọ́n fọ ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní oúnjẹ. +Lẹ́yìn náà wọ́n tọ́jú ẹ̀bùn Josẹfu sílẹ̀ di ìgbà tí yóo dé lọ́sàn-án, nítorí wọ́n gbọ́ pé ibẹ̀ ni wọn yóo ti jẹun. +Nígbà tí Josẹfu wọlé, wọ́n mú ẹ̀bùn tí wọ́n mú bọ̀ fún un wọlé tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n sì wólẹ̀ fún un, wọ́n dojúbolẹ̀. +Ó bèèrè alaafia wọn, ó ní, “Ṣé alaafia ni baba yín wà, arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi? Ṣé ó ṣì wà láàyè?” +Wọ́n dá a lóhùn, wọ́n ní, “Baba wa, iranṣẹ rẹ ń bẹ láàyè, ó sì wà ní alaafia.” Wọ́n tẹríba, wọ́n bu ọlá fún un. +Ojú tí ó gbé sókè, ó rí Bẹnjamini ọmọ ìyá rẹ̀, ó bá bèèrè pé, “Ṣé arakunrin yín tí í ṣe àbíkẹ́yìn tí ẹ wí nìyí? Kí Ọlọrun fi ojurere wò ọ́, ọmọ mi.” +Ṣugbọn Juda dá a lóhùn, ó ní, “Ọkunrin náà kìlọ̀ fún wa gidigidi pé a kò ní fi ojú kan òun láìjẹ́ pé a mú arakunrin wa lọ́wọ́. +Josẹfu bá yára jáde kúrò lọ́dọ̀ wọn nítorí pé ọkàn rẹ̀ fà sí àbúrò rẹ̀, orí rẹ̀ sì wú, ó wá ibìkan láti lọ sọkún. Ó bá wọ yàrá rẹ̀, ó lọ sọkún níbẹ̀. +Lẹ́yìn náà ó bọ́ ojú rẹ̀, ó jáde, ó gbìyànjú, ó dárayá, ó ní, “Ẹ gbé oúnjẹ wá.” +Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ kalẹ̀ lọ́tọ̀, ti àwọn arakunrin rẹ̀ lọ́tọ̀, ati ti àwọn ará Ijipti tí wọn ń bá a jẹun lọ́tọ̀, nítorí pé ìríra ni ó jẹ́ fún àwọn ará Ijipti láti bá àwọn Heberu jẹun pọ̀. +Àwọn arakunrin Josẹfu jókòó níwájú rẹ̀, wọ́n tò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí wọn, láti orí ẹ̀gbọ́n patapata dé orí àbúrò patapata. Nígbà tí àwọn arakunrin Josẹfu rí i bí wọ́n ti tò wọ́n, wọ́n ń wo ara wọn lójú tìyanu-tìyanu. +Láti orí tabili Josẹfu ni wọ́n ti bu oúnjẹ fún olukuluku, ṣugbọn oúnjẹ ti Bẹnjamini tó ìlọ́po marun-un ti ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n bá a jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì bá a ṣe àríyá. +Bí o bá jẹ́ kí arakunrin wa bá wa lọ, a óo lọ ra oúnjẹ wá fún ọ, +ṣugbọn bí o kò bá jẹ́ kí ó bá wa lọ, a kò ní lọ, nítorí pé ọkunrin náà tẹnumọ́ ọn fún wa pé a kò ní fi ojú kan òun láìjẹ́ pé arakunrin wa bá wa wá.” +Israẹli ní, “Irú ọ̀ràn ńlá wo ni ẹ tún dá sí mi lọ́rùn yìí, tí ẹ lọ sọ fún ọkunrin náà pé ẹ ní arakunrin mìíràn?” +Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò sí ohun tí ọkunrin náà kò bi wá tán nípa ará ati ẹbí wa, ó ní, ‘Ǹjẹ́ baba yín wà láàyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arakunrin mìíràn?’ Àwọn ìbéèrè tí ó ń bèèrè ni ó mú kí á sọ ohun tí a sọ fún un. Báwo ni a ṣe lè mọ̀ pé yóo sọ pé kí á mú àbúrò wa wá?” +Juda bá sọ fún Israẹli, ó ní, “Fa ọmọ náà lé mi lọ́wọ́, a óo sì lọ kí á lè wà láàyè, kí ebi má baà pa ẹnikẹ́ni kú ninu wa, ati àwọn ọmọ wa kéékèèké. +N óo dúró fún ọmọ náà, ọwọ́ mi ni kí o ti bèèrè rẹ̀. Bí n kò bá mú un pada, kí n sì fà á lé ọ lọ́wọ́, da ẹ̀bi rẹ̀ lé mi lórí títí lae, +Àwọn Arakunrin Josẹfu Pada Lọ sí Ijipti pẹlu Bẹnjamini. +Josẹfu pàṣẹ fún alabojuto ilé rẹ̀, ó ní, “Ẹ di ọkà kún àpò àwọn ọkunrin wọnyi, bí wọ́n bá ti lè rù tó, kí ẹ sì fi owó olukuluku wọn sí ẹnu àpò rẹ̀, +Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ ti wí gan-an ni yóo rí. Ọwọ́ ẹni tí a bá ti bá a ni yóo di ẹrú mi, kò sí ohun tí ó kan ẹ̀yin yòókù rárá.” +Gbogbo wọn bá sọ àpò wọn kalẹ̀, wọ́n tú wọn. +Iranṣẹ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí wo àpò wọn, ó bẹ̀rẹ̀ lórí àpò èyí àgbà patapata, títí dé orí ti àbíkẹ́yìn wọn, wọ́n bá ife náà ninu ẹrù Bẹnjamini. +Wọ́n fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, olukuluku wọn bá di ẹrù rẹ̀ ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, wọ́n pada lọ sí ààrin ìlú. +Nígbà tí Juda ati àwọn arakunrin rẹ̀ pada dé ilé Josẹfu, ó ṣì wà nílé, wọ́n bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú rẹ̀. +Josẹfu bi wọ́n léèrè, ó ní, “Irú kí ni ẹ dánwò yìí? Ó jọ bí ẹni pé ẹ kò lérò pé irú mi lè woṣẹ́ ni?” +Juda dá a lóhùn, ó ní, “Kí ni a rí tí a lè wí fún ọ, oluwa mi? Ọ̀rọ̀ wo ni ó lè dùn lẹ́nu wa? Ọṣẹ wo ni a lè fi wẹ̀, tí a fi lè mọ́? Ọlọrun ti rí ẹ̀bi àwa iranṣẹ rẹ. Wò ó, a di ẹrú rẹ, oluwa mi, ati àwa ati ẹni tí wọ́n bá ife náà lọ́wọ́ rẹ̀.” +Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Kí á má rí i pé mo ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀. Ẹnìkan ṣoṣo tí wọ́n ká ife náà mọ́ lọ́wọ́ ni yóo di ẹrú mi, ní tiyín, ẹ máa pada tọ baba yín lọ ní alaafia.” +Juda bá tọ̀ ọ́ lọ, ó ní, “Jọ̀wọ́, oluwa mi, jẹ́ kí n sọ gbolohun ọ̀rọ̀ kan, má jẹ́ kí inú bí ọ sí èmi, iranṣẹ rẹ, nítorí kò sí ìyàtọ̀, bíi Farao ni o rí. +Oluwa mi, ranti pé o bi àwa iranṣẹ rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ẹ ní baba tabi arakunrin mìíràn?’ +kí ẹ wá fi ife fadaka mi sí ẹnu àpò èyí àbíkẹ́yìn wọn, pẹlu owó tí ó fi ra ọkà.” Ọkunrin náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti pàṣẹ fún un. +A sì dá oluwa mi lóhùn pé, ‘A ní baba, ó ti di arúgbó, a sì ní arakunrin kan pẹlu, tí baba yìí fi arúgbó ara bí, ati pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ṣoṣo ni ó kù lọ́mọ ìyá tirẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn rẹ̀.’ +O sọ fún àwa iranṣẹ rẹ pé kí á mú un tọ̀ ọ́ wá, kí o lè fi ojú rí i. +A sì sọ fún ọ pé, ‘Ọmọ náà kò lè fi baba rẹ̀ sílẹ̀, nítorí pé bí ó bá fi baba rẹ̀ sílẹ̀, baba rẹ̀ yóo kú.’ +O bá sọ fún àwa iranṣẹ rẹ pé bí àbíkẹ́yìn wa patapata kò bá bá wa wá, a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ mọ́. +“Nígbà tí a pada dé ọ̀dọ̀ baba wa, iranṣẹ rẹ, a rò fún un bí o ti wí. +Nígbà tí ó ní kí á tún lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá, +a wí fún un pé, a kò ní lọ, àfi bí arakunrin wa bá tẹ̀lé wa, nítorí pé a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ bí kò bá bá wa wá. +Baba wa sọ fún wa pé a mọ̀ pé ọkunrin meji ni Rakẹli, aya òun bí fún òun, +ọ̀kan fi òun sílẹ̀, òun sì wí pé, dájúdájú, ẹranko kan ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, òun kò sì tíì fi ojú òun kàn án láti ìgbà náà. +Ó ní bí a bá tún mú eléyìí kúrò lọ́dọ̀ òun, bí ohun burúkú kan bá ṣẹlẹ̀ sí i, pẹlu arúgbó ara òun yìí, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo pa òun. +Bí ilẹ̀ ọjọ́ keji ti mọ́, wọ́n ní kí àwọn arakunrin Josẹfu máa lọ ati àwọn ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. +“Nítorí náà, bí mo bá pada dé ọ̀dọ̀ baba mi tí n kò sì mú ọmọdekunrin náà lọ́wọ́, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ọmọdekunrin yìí gan-an ni ó fi ẹ̀mí tẹ̀, +bí kò bá rí i pẹlu wa, kíkú ni yóo kú. Yóo sì wá jẹ́ pé àwa ni a fa ìbànújẹ́ fún baba wa, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ìbànújẹ́ yìí ni yóo sì pa á. +Èmi ni mo dúró fún ọmọdekunrin náà lọ́dọ̀ baba wa, mo wí fún un pé, ‘Bí n kò bá mú ọmọ yìí pada, ẹ̀bi rẹ̀ yóo wà lórí mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.’ +Nígbà tí ọ̀rọ̀ wá rí bí ó ti rí yìí, oluwa mi, jọ̀wọ́, jẹ́ kí èmi di ẹrú rẹ dípò ọmọdekunrin yìí, jẹ́ kí òun máa bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pada lọ. +Báwo ni n óo ṣe pada dé iwájú baba mi láìmú ọmọ náà lọ́wọ́? Ẹ̀rù ohun burúkú tí yóo ṣẹlẹ̀ sí baba mi, ń bà mí.” +Nígbà tí wọn kò tíì rìn jìnnà sí ìlú, Josẹfu sọ fún alabojuto ilé rẹ̀ pé, “Gbéra, sáré tẹ̀lé àwọn ọkunrin náà, nígbà tí o bá bá wọn, wí fún wọn pé, ‘Èéṣe tí ẹ fi fi ibi sú olóore? Èéṣe tí ẹ fi jí ife fadaka ọ̀gá mi? +Ife yìí ni ọ̀gá mi fi ń mu omi, ife yìí kan náà ni ó sì fi ń woṣẹ́, ọ̀ràn ńlá gan-an ni ẹ dá yìí.’ ” +Nígbà tí ó lé wọn bá, ó wí fún wọn bí Josẹfu ti kọ́ ọ. +Wọ́n dá a lóhùn, wọ́n ní, “Èéṣe tí o fi ń sọ̀rọ̀ sí wa báyìí? Kí á má rí i, pé àwa iranṣẹ rẹ ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀. +Ṣé o ranti pé owó tí a bá lẹ́nu àpò wa, a mú un pada ti ilẹ̀ Kenaani wá fún ọ? Kí ni ìbá dé tí a óo fi jí fadaka tabi wúrà ní ilé ọ̀gá rẹ? +Bí wọ́n bá bá a lọ́wọ́ èyíkéyìí ninu àwa iranṣẹ rẹ, pípa ni kí wọ́n pa olúwarẹ̀, kí àwa yòókù sì di ẹrú rẹ.” +Ife Tí Ó Sọnù. +Josẹfu kò lè mú ọ̀rọ̀ yìí mọ́ra mọ́ lójú gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá kígbe, ó ní, “Gbogbo yín patapata, ẹ jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.” Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ Josẹfu nígbà tí ó fi ara rẹ̀ han àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu. +Ẹ sọ fún un pé mo sọ pé kí ó wá máa gbé ní ilẹ̀ Goṣeni nítòsí mi, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ati agbo mààlúù rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní. +N óo máa tọ́jú rẹ̀ níbẹ̀, nítorí pé ó tún ku ọdún marun-un gbáko kí ìyàn yìí tó kásẹ̀ nílẹ̀, kí òun ati ìdílé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ má baà di aláìní. +“Ẹ̀yin pàápàá fi ojú rí i, Bẹnjamini arakunrin mi náà sì rí i pẹlu pé èmi gan-an ni mò ń ba yín sọ̀rọ̀. +Ẹ níláti sọ fún baba mi nípa gbogbo ògo mi ní Ijipti, ati gbogbo ohun tí ẹ ti rí. Ẹ tètè yára mú baba mi wá bá mi níhìn-ín.” +Ó bá rọ̀ mọ́ Bẹnjamini arakunrin rẹ̀ lọ́rùn, ó sì bú sẹ́kún, bí Bẹnjamini náà ti rọ̀ mọ́ ọn, ni òun náà bú sẹ́kún. +Josẹfu bá fi ẹnu ko àwọn arakunrin rẹ̀ lẹ́nu lọ́kọ̀ọ̀kan, ó sì sọkún, lẹ́yìn náà ni àwọn arakunrin rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ̀rọ̀. +Nígbà tí gbogbo ìdílé Farao gbọ́ pé àwọn arakunrin Josẹfu dé, inú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ dùn pupọ. +Farao sọ fún Josẹfu pé kí ó sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ kí wọ́n múra, kí wọ́n di ẹrù ru àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, kí wọ́n tètè pada lọ sí Kenaani, +kí wọ́n sì lọ mú baba rẹ̀ ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ wá sọ́dọ̀ òun. Ó ní òun óo fún un ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, wọn yóo sì jẹ àjẹyó ninu ilẹ̀ náà. +Ó ní kí Josẹfu pàṣẹ fún wọn pẹlu kí wọ́n kó kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi kó àwọn ọmọde ati àwọn obinrin, kí baba wọn náà sì máa bá wọn bọ̀. +Ó bú sẹ́kún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pohùnréré ẹkún tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti ati gbogbo ilé Farao gbọ́ ẹkún rẹ̀. +Ó ní kí wọ́n má ronú àwọn dúkìá wọn nítorí àwọn ni wọn yóo ni ilẹ̀ tí ó dára jù ní Ijipti. +Àwọn ọmọ Israẹli ṣe bí ọba ti wí, Josẹfu fún wọn ní kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Farao, ó sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọn yóo máa jẹ lọ́nà. +Ó fún olukuluku wọn ní ìpààrọ̀ aṣọ kọ̀ọ̀kan, ṣugbọn ó fún Bẹnjamini ní ọọdunrun (300) ṣekeli fadaka ati ìpààrọ̀ aṣọ marun-un. +Ó di àwọn nǹkan dáradára ilẹ̀ Ijipti ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá, ó di ọkà ati oúnjẹ ru abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá, ó kó wọn ranṣẹ sí baba rẹ̀ pé kí ó rí ohun máa jẹ bọ̀ lọ́nà. +Ó bá ní kí àwọn arakunrin òun máa lọ, bí wọ́n sì ti fẹ́ máa lọ, ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má bá ara wọn jà lọ́nà. +Wọ́n bá kúrò ní Ijipti, wọ́n pada sọ́dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani. +Wọ́n sọ fún un pé, “Josẹfu kò kú, ó wà láàyè, ati pé òun ni alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti.” Nígbà tí ó gbọ́ bẹ́ẹ̀, orí rẹ̀ fò lọ fee, kò kọ́ gbà wọ́n gbọ́. +Ṣugbọn nígbà tí ó gbọ́ gbogbo ohun tí Josẹfu wí fún wọn, tí ó tún rí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin tí Josẹfu fi ranṣẹ pé kí wọ́n fi gbé òun wá, ara rẹ̀ wálẹ̀. +Israẹli bá dáhùn, ó ní, “Josẹfu, ọmọ mi wà láàyè! Ó ti parí, n óo lọ fi ojú kàn án kí n tó kú.” +Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu. Ó bi wọ́n léèrè pé ǹjẹ́ baba òun ṣì wà láàyè. Ṣugbọn jìnnìjìnnì dà bo àwọn arakunrin rẹ̀ níwájú rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè dáhùn. +Josẹfu bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ wọ́n, ó ní kí wọ́n jọ̀wọ́, kí wọ́n súnmọ́ òun. Ó tún wí fún wọn pé òun ni Josẹfu arakunrin wọn, tí wọ́n tà sí Ijipti. +Ó ní, “Ẹ má wulẹ̀ dààmú ẹ̀mí ara yín, ẹ má sì bínú sí ara yín pé ẹ tà mí síhìn-ín. Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó rán mi ṣáájú yín láti gba ẹ̀mí là. +Nítorí ó ti di ọdún keji tí ìyàn yìí ti bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ yìí, ó sì ku ọdún marun-un gbáko tí kò fi ní sí ìfúrúgbìn tabi ìkórè. +Ọlọrun ni ó rán mi ṣáájú yín láti dá yín sí, ati láti gba ọpọlọpọ ẹ̀mí là ninu ìran yín. +Nítorí náà, kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé mi dé ìhín, Ọlọrun ni, ó sì ti fi mí ṣe baba fún Farao, ati oluwa ninu gbogbo ilé rẹ̀ ati al��kòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti. +“Ẹ ṣe kíá, ẹ wá lọ sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ wí fún un pé, Josẹfu ọmọ rẹ̀ wí pé, Ọlọrun ti fi òun ṣe olórí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, ẹ ní mo ní kí ó máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi kíákíá. +Josẹfu Farahan Àwọn Arakunrin Rẹ̀. +Israẹli di gbogbo ohun tí ó ní, ó kó lọ sí Beeriṣeba, ó lọ rúbọ sí Ọlọrun Isaaki, baba rẹ̀. +Àwọn ọmọ ti Simeoni ni: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari, ati Ṣaulu, tí obinrin ará Kenaani bí fún un. +Àwọn ọmọ ti Lefi ni: Geriṣoni, Kohati, ati Merari. +Àwọn ọmọ ti Juda ni: Eri, Onani, Ṣela, Peresi, ati Sera, (ṣugbọn, Eri ati Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani) àwọn ọmọ ti Peresi ni Hesironi ati Hamuli. +Àwọn ọmọ ti Isakari ni: Tola, Pua, Jobu ati Ṣimironi. +Àwọn ọmọ ti Sebuluni ni: Seredi, Eloni, ati Jaleeli. +(Àwọn ni ọmọ tí Lea bí fún Jakọbu ní Padani-aramu ati Dina, ọmọ rẹ̀ obinrin.) Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin jẹ́ mẹtalelọgbọn. +Àwọn ọmọ ti Gadi ni: Sifioni, Hagi, Ṣuni, Esiboni, Eri, Arodu, ati Areli. +Àwọn ọmọ ti Aṣeri ni: Imina, Iṣifa, Iṣifi, Beraya, ati Sera arabinrin wọn. Àwọn ọmọ ti Beraya ni Heberi, ati Malikieli. +(Àwọn ni ọmọ tí Silipa bí fún Jakọbu. Silipa ni iranṣẹ tí Labani fún Lea ọmọ rẹ̀ obinrin, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹrindinlogun.) +Àwọn ọmọ ti Rakẹli ni Josẹfu ati Bẹnjamini. +Ọlọrun bá a sọ̀rọ̀ lójú ìran lóru, ó pè é, ó ní, “Jakọbu, Jakọbu.”Ó dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.” +Asenati, ọmọbinrin Pọtifera bí Manase ati Efuraimu fún Josẹfu ní ilẹ̀ Ijipti. Pọtifera ni babalóòṣà oriṣa Oni, ní Ijipti. +Àwọn ọmọ ti Bẹnjamini ni: Bela, Bekeri, Aṣibeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Hupimu, ati Aridi, +(àwọn wọnyi ni ọmọ tí Rakẹli bí fún Jakọbu ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹrinla). +Ọmọ ti Dani ni Huṣimu. +Àwọn ọmọ ti Nafutali ni Jaseeli, Guni, Jeseri, ati Ṣilemu. +(Àwọn ọmọ tí Biliha bí fún Jakọbu ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ jẹ́ meje), Biliha ni iranṣẹbinrin tí Labani fún Rakẹli, ọmọ rẹ̀ obinrin. +Gbogbo àwọn tí wọ́n bá Jakọbu lọ sí Ijipti, tí wọ́n jẹ́ ọmọ tabi ọmọ ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹrindinlaadọrin, láìka àwọn iyawo àwọn ọmọ rẹ̀. +Àwọn ọmọ tí Josẹfu bí ní Ijipti jẹ́ meji. Gbogbo eniyan tí ó ti ìdílé Jakọbu jáde lọ sí Ijipti patapata wá jẹ́ aadọrin. +Jakọbu rán Juda ṣáájú lọ sọ́dọ̀ Josẹfu pé kí Josẹfu wá pàdé òun ní Goṣeni, wọ́n sì wá sí ilẹ̀ Goṣeni. +Josẹfu bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ó lọ pàdé Israẹli, baba rẹ̀ ní Goṣeni. Nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ baba rẹ̀, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì sọkún fún ìgbà pípẹ́. +Ọlọrun wí pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, má fòyà rárá láti lọ sí Ijipti, nítorí pé n óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. +Israẹli bá wí fún Josẹfu, ó ní, “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ojú kàn ọ́ báyìí, tí mo sì rí i pé o wà láàyè, bí ikú bá tilẹ̀ wá dé, ó yá mi.” +Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo ìdílé baba rẹ̀ pé òun óo lọ sọ fún Farao pé àwọn arakunrin òun ati ìdílé baba òun tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Kenaani ti dé sọ́dọ̀ òun. +Ati pé darandaran ni wọ́n, ìtọ́jú ẹran ọ̀sìn ni iṣẹ́ wọn, wọ́n sì kó gbogbo agbo mààlúù ati agbo ewúrẹ́, ati ohun gbogbo tí wọ́n ní lọ́wọ́ wá. +Ó ní nígbà tí Farao bá pè wọ́n, tí ó bá bi wọ́n léèrè pé irú iṣẹ́ wo ni wọ́n ń ṣe, +kí wọ́n dá a lóhùn pé, ẹran ọ̀sìn ni àwọn ti ń tọ́jú láti ìgbà èwe àwọn títí di ìsinsìnyìí, ati àwọn ati àwọn baba àwọn, kí ó lè jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé ìríra patapata ni gbogbo darandaran jẹ́ fún àwọn ará Ijipti. +N óo bá ọ lọ sí Ijipti, n óo sì tún mú ọ pada wá, ọwọ́ Josẹfu ni o óo sì dákẹ́ sí.” +Jakọbu bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Beeriṣeba. Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé e sinu ọkọ̀ tí Farao fi ranṣẹ sí i pé kí wọ́n fi gbé e wá, wọ́n sì kó àwọn iyawo wọn ati àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ pẹlu wọn. +Wọ́n kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun tí wọ́n ní ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n lọ sí Ijipti. +Gbogbo ilé rẹ̀ patapata ni Jakọbu kó lọ́wọ́ lọ sí Ijipti, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, gbogbo wọn ni ó kó lọ sí Ijipti patapata. +Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Israẹli tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀: Reubẹni, àkọ́bí rẹ̀, +ati àwọn ọmọ Reubẹni wọnyi: Hanoku, Palu, Hesironi, ati Karimi. +Jakọbu ati Ìdílé Rẹ̀ Lọ sí Ijipti. +Josẹfu bá wọlé lọ sọ fún Farao pé, “Baba mi ati àwọn arakunrin mi ti dé láti ilẹ̀ Kenaani, pẹlu gbogbo agbo ẹran ati agbo mààlúù wọn, ati ohun gbogbo tí wọ́n ní, wọ́n sì wà ní ilẹ̀ Goṣeni báyìí.” +Jakọbu súre fún Farao ó sì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. +Josẹfu bá fi baba ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, ninu ilẹ̀ Ramesesi, gẹ́gẹ́ bí Farao ti pa á láṣẹ. +Josẹfu pèsè ohun jíjẹ fún baba ati àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye eniyan tí olukuluku wọn ń bọ́. +Ìyàn náà mú tóbẹ́ẹ̀ tí ìdààmú bá gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kenaani nítorí pé kò sí oúnjẹ rárá ní ilẹ̀ Kenaani. +Gbogbo owó tí àwọn ará ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ará ilẹ̀ Kenaani ní patapata ni wọ́n kó tọ Josẹfu wá láti fi ra oúnjẹ. Josẹfu sì kó gbogbo owó náà lọ fún Farao. +Nígbà tí kò sí owó mọ́ rárá ní ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kenaani, gbogbo àwọn ará Ijipti tọ Josẹfu lọ, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ. Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran báyìí títí tí a óo fi kú? Kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá.” +Josẹfu bá dá wọn lóhùn pé, “Bí kò bá sí owó lọ́wọ́ yín mọ́, ẹ kó àwọn ẹran ọ̀sìn yín wá, n óo sì fun yín ní oúnjẹ dípò wọn.” +Wọ́n bá kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tọ Josẹfu lọ, Josẹfu sì fún wọn ní oúnjẹ dípò àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, agbo ẹran wọn, agbo mààlúù wọn ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó fi àwọn ẹran ọ̀sìn wọn dí oúnjẹ fún wọn ní ọdún náà. +Nígbà tí ọdún náà parí, wọ́n tún wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní ọdún keji, wọ́n ní, “A kò jẹ́ purọ́ fún oluwa wa, pé kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá, gbogbo agbo ẹran wa sì ti di tìrẹ, a kò ní ohunkohun mọ́ àfi ara wa ati ilẹ̀ wa. +Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran títí tí a óo fi kú, ati àwa, ati ilẹ̀ wa? Fi oúnjẹ ra àwa ati ilẹ̀ wa, a óo sì di ẹrú Farao. Fún wa ní irúgbìn, kí á lè wà láàyè, kí ilẹ̀ yìí má baà di ahoro.” +Ó mú marun-un ninu àwọn arakunrin rẹ̀, ó fi wọ́n han Farao. +Josẹfu bá ra gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún Farao, nítorí pé gbogbo àwọn ará Ijipti ni wọ́n ta ilẹ̀ wọn, nítorí ìyàn náà dà wọ́n láàmú pupọ. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ilẹ̀ Ijipti ṣe di ti Farao, +ó sì sọ àwọn eniyan náà di ẹrú rẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ Ijipti. +Àfi ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kò rà, nítorí pé ó ní iye tí Farao máa ń fún wọn nígbàkúùgbà. Ohun tí Farao ń fún wọn yìí ni wọ́n sì fi ń jẹun. Ìdí nìyí tí kò jẹ́ kí wọ́n ta ilẹ̀ wọn. +Josẹfu sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Àtẹ̀yin, àtilẹ̀ yín, láti òní lọ, mo ra gbogbo yín fún Farao. Irúgbìn nìyí, ẹ lọ gbìn ín sinu oko yín. +Nígbà tí ẹ bá kórè, ẹ óo pín gbogbo ohun tí ẹ bá kórè sí ọ̀nà marun-un, ìpín kan jẹ́ ti Farao, ìpín mẹrin yòókù yóo jẹ́ tiyín. Ninu rẹ̀ ni ẹ óo ti mú irúgbìn, ati èyí tí ẹ óo máa jẹ, ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín pẹlu àwọn ọmọ yín.” +Wọ́n dáhùn pé, “Ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ ikú, bí ó bá ti wù ọ́ bẹ́ẹ̀, a óo di ẹrú Farao.” +Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe sọ ọ́ di òfin ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì wà títí di òní olónìí pé ìdámárùn-ún gbogbo ìkórè oko jẹ́ ti Farao, ati pé ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kì í ṣe ti Farao. +Israẹli ń gbé ilẹ̀ Ijipti, ní Goṣeni, wọ́n sì ní ọpọlọpọ ohun ìní níbẹ̀, wọ́n bímọ lémọ, wọ́n sì pọ̀ sí i gidigidi. +Ọdún mẹtadinlogun ni Jakọbu gbé sí i ní ilẹ̀ Ijipti, gbogbo ọdún tí ó gbé láyé sì jẹ́ ọdún mẹtadinlaadọjọ (147). +Nígbà tí àkókò tí Jakọbu yóo kú súnmọ́ tòsí, ó pe Josẹfu ọmọ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Wá, ti ọwọ́ rẹ bọ abẹ́ itan mi, kí o sì ṣèlérí pé o óo ṣe olóòótọ́ sí mi, o kò sì ní dà mí. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Ijipti, +Farao bi àwọn arakunrin rẹ̀ léèrè irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.Wọ́n dá Farao lóhùn pé, darandaran ni àwọn gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn. +ṣugbọn gbé mi kúrò ní ilẹ̀ Ijipti kí o sì sin mí sí ibojì àwọn baba mi. Ibi tí wọ́n sin wọ́n sí ni mo fẹ́ kí o sin èmi náà sí.”Josẹfu dáhùn, ó ní, “Mo gbọ́, n óo ṣe bí o ti wí.” +Jakọbu ní kí Josẹfu búra fún òun, Josẹfu sì búra fún un. Nígbà náà ni Jakọbu tẹríba lórí ibùsùn rẹ̀. +Wọ́n tún wí fún Farao pé, àwọn wá láti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ rẹ̀ ni, nítorí pé ìyàn ńlá tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani kò jẹ́ kí koríko wà fún àwọn ẹran àwọn. Wọ́n ní àwọn wá bẹ Farao ni, pé kí ó jẹ́ kí àwọn máa gbé ilẹ̀ Goṣeni. +Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Ọ̀dọ̀ rẹ ni baba rẹ ati àwọn arakunrin rẹ wá. +Wo ilẹ̀ Ijipti láti òkè dé ilẹ̀, ibikíbi tí o bá rí i pé ó dára jùlọ ninu gbogbo ilẹ̀ náà ni kí o fi baba rẹ ati àwọn arakunrin rẹ sí. Jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, bí o bá sì mọ èyíkéyìí ninu wọn tí ó lè bojútó àwọn ẹran ọ̀sìn dáradára, fi ṣe alabojuto àwọn ẹran ọ̀sìn mi.” +Josẹfu bá mú Jakọbu baba rẹ̀ wọlé láti fihan Farao, Jakọbu sì súre fún Farao. +Farao bi Jakọbu pé, “Ẹni ọdún mélòó ni ọ́ báyìí?” +Jakọbu dá a lóhùn pé, “Ọjọ́ orí mi jẹ́ aadoje (130) ọdún. Ọjọ́ orí mi kò tó nǹkan rárá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú mi ti rí ọpọlọpọ ibi. Ọjọ́ orí mi kò tíì dé ibìkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti àwọn baba mi.” +Àkókò Ìyàn. +Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún Josẹfu pé ara baba rẹ̀ kò yá, Josẹfu bá mú àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Manase ati Efuraimu, lọ́wọ́ lọ bẹ baba rẹ̀ wò. +Ogbó ti mú kí ojú Israẹli di bàìbàì ní àkókò yìí, kò sì ríran dáradára mọ́. Josẹfu bá kó wọn súnmọ́ baba rẹ̀, baba rẹ̀ dì mọ́ wọn, ó sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu. +Ó wí fún Josẹfu pé, “N kò lérò pé mo tún lè fi ojú kàn ọ́ mọ́, ṣugbọn Ọlọrun mú kí ó ṣeéṣe fún mi láti rí àwọn ọmọ rẹ.” +Josẹfu bá kó wọn kúrò lẹ́sẹ̀ baba rẹ̀, òun gan-an náà wá dojúbolẹ̀ níwájú baba rẹ̀. +Ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú Efuraimu, ó fà á súnmọ́ ẹ̀gbẹ́ ọwọ́ òsì baba rẹ̀, ó fi ọwọ́ òsì mú Manase, ó fà á súnmọ́ ẹ̀gbẹ́ ọwọ́ ọ̀tún baba rẹ̀. +Ṣugbọn nígbà tí Israẹli na ọwọ́ rẹ̀ láti súre fún wọn, ó dábùú ọwọ́ rẹ̀ lórí ara wọn, ó gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efuraimu lórí, ó sì gbé ọwọ́ òsì lé Manase lórí, bẹ́ẹ̀ ni Efuraimu ni àbúrò, Manase sì ni àkọ́bí. +Ó bá súre fún Josẹfu, ó ní,“Kí Ọlọrun tí Abrahamu ati Isaaki, baba mi, ń sìn bukun àwọn ọmọ wọnyi,kí Ọlọrun náà tí ó ti ń tọ́ mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní yìí bukun wọn, +kí angẹli tí ó yọ mí ninu gbogbo ewu bukun wọn;kí ìrántí orúkọ mi, ati ti Abrahamu, ati ti Isaaki, àwọn baba mi, wà ní ìran wọn títí ayé,kí atọmọdọmọ wọn pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.” +Nígbà tí Josẹfu rí i pé ọwọ́ ọ̀tún ni baba òun gbé lé Efuraimu lórí, kò dùn mọ́ ọn. Ó bá di ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé e kúrò lórí Efuraimu kí ó sì gbé e lórí Manase. +Ó wí fún baba rẹ̀ pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, baba, eléyìí ni àkọ́bí, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé e lórí.” +Ṣugbọn baba rẹ̀ kọ̀, ó ní, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀, òun náà yóo di eniyan, yóo sì di alágbára, ṣugbọn sibẹsibẹ àbúrò rẹ̀ yóo jù ú lọ, àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ yóo sì di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè.” +Nígbà tí wọ́n sọ fún Jakọbu pé Josẹfu ọmọ rẹ̀ dé, ó ṣe ara gírí, ó jókòó lórí ibùsùn rẹ̀. +Ó bá súre fún wọn ní ọjọ́ náà, ó ní, “Orúkọ yín ni Israẹli yóo fi máa súre fún eniyan,wọn yóo máa súre pé,‘Kí Ọlọrun kẹ́ ọ bí ó ti kẹ́ Efuraimu ati Manase.’ ”Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi Efuraimu ṣáájú Manase. +Nígbà náà ni Israẹli sọ fún Josẹfu pé, “Àkókò ikú mi súnmọ́ etílé, ṣugbọn Ọlọrun yóo wà pẹlu rẹ, yóo sì mú ọ pada sí ilẹ̀ baba rẹ. +Dípò kí n fún àwọn arakunrin rẹ ní Ṣekemu, tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ òkè, níbi tí mo jagun gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori, ìwọ ni mo fún.” +Jakọbu sọ fún Josẹfu pé, “Ọlọrun Olodumare farahàn mí ní Lusi ní ilẹ̀ Kenaani, ó sì súre fún mi. +Ó ní, ‘N óo fún ọ ní ọpọlọpọ ọmọ, n óo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ ẹ̀yà, ati pé àwọn ọmọ ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ náà fún, yóo sì jẹ́ tiwọn títí ayé.’ +“Tèmi ni àwọn ọmọkunrin mejeeji tí o bí ní ilẹ̀ Ijipti kí n tó dé, bí Reubẹni ati Simeoni ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ náà ni Manase ati Efuraimu jẹ́ tèmi. +Àwọn ọmọ tí o bá tún bí lẹ́yìn wọn, ìwọ ni o ni wọ́n, ninu ogún tí ó bá kan Manase ati Efuraimu ni wọn yóo ti pín. +Ìbànújẹ́ ni ó jẹ́ fún mi pé nígbà tí mò ń ti Padani-aramu bọ̀, Rakẹli kú lọ́nà, ní ilẹ̀ Kenaani, ibi tí ó dákẹ́ sí kò jìnnà pupọ sí Efurati. Lójú ọ̀nà Efurati náà ni mo sì sin ín sí.” (Efurati yìí ni wọ́n ń pè ní Bẹtilẹhẹmu.) +Nígbà tí Israẹli rí àwọn ọmọ Josẹfu, ó bèèrè pé, “Àwọn wo nìyí?” +Josẹfu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Àwọn ọmọ mi, tí Ọlọrun pèsè fún mi níhìn-ín ni wọ́n.”Jakọbu bá wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí wọ́n súnmọ́ mi kí n lè súre fún wọn.” +Jakọbu Súre fún Efuraimu ati Manase. +Jakọbu ranṣẹ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ kó ara yín jọ kí n lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín ní ọjọ́ iwájú fún yín. +Ọ̀pá àṣẹ ọba kì yóo kúrò ní ilé Juda,arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo sì máa jọba,títí tí yóo fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ni ín;gbogbo ìran eniyan ni yóo sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. +Yóo máa so ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà,yóo so àwọ́nsìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà dáradára,bẹ́ẹ̀ ni oje àjàrà ni yóo máa fi fọ ẹ̀wù rẹ̀. +Ojú rẹ̀ yóo pọ́n fún àmutẹ́rùn ọtí waini,eyín rẹ̀ yóo sì funfun fún àmutẹ́rùn omi wàrà. +“Sebuluni yóo máa gbé etí òkun,ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ kò ní níye,Sidoni ni yóo jẹ́ ààlà rẹ̀. +“Isakari dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó lágbáratí ó dùbúlẹ̀ láàrin gàárì ẹrù rẹ̀. +Ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé ibi ìsinmi dáraati pé ilẹ̀ náà dára,ó tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ láti ru ẹrù,ó sì di ẹni tí wọn ń mú sìn bí ẹrú. +Dani ni yóo máa ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli. +Dani yóo dàbí ejò lójú ọ̀nà,ati bíi paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà,tí ń bu ẹṣin ní gìgísẹ̀ jẹ,kí ẹni tí ó gùn ún lè ṣubú sẹ́yìn. +Mo dúró de ìgbàlà rẹ, Oluwa. +Àwọn olè yóo máa kó Gadi lẹ́rù,ṣugbọn bí wọ́n ti ń kó o,bẹ́ẹ̀ ni yóo sì máa gbà á pada. +Ẹ péjọ kí ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,kí ẹ sì fetí sí ọ̀rọ̀ Israẹli, baba yín. +Aṣeri yóo máa rí oúnjẹ dáradára mú jáde ninu oko rẹ̀,oúnjẹ ọlọ́lá ni yóo máa ti inú oko rẹ̀ jáde. +Nafutali dàbí àgbọ̀nrín tí ń sáré káàkiri,tí ó sì ní àwọn ọmọ tí ó lẹ́wà. +Josẹfu dàbí igi eléso tí ó wà lẹ́bàá odò,àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà mọ́ ara ògiri. +Àwọn tafàtafà gbógun tì í kíkankíkan,wọ́n ń ta á lọ́fà, wọ́n sì ń dà á láàmú gidigidi, +sibẹsibẹ ọrùn rẹ̀ kò mì,apá rẹ̀ sì ń lágbára sí i.Agbára Ọlọrun Jakọbu ni ó fún apá rẹ̀ ní okun,(ní orúkọ Olùṣọ́-aguntan náà,tí í ṣe Àpáta ààbò Israẹli), +Ọlọrun baba rẹ yóo ràn ọ́ lọ́wọ́.Ọlọrun Olodumare yóo rọ òjò ibukun sórí rẹ láti òkè ọ̀run wá,yóo sì fún ọ ní ibukun omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀,ati ọpọlọpọ ọmọ ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn. +Ibukun àwọn baba rẹ ju ti àwọn òkè ayérayé lọ,kí ibukun àwọn òkè ayérayé wá sórí Josẹfu,ẹni tí wọ́n yà ní ipá lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀. +“Bẹnjamini dàbí ìkookò tí ebi ń pa,a máa pa ohun ọdẹ rẹ̀ ní òwúrọ̀,ati ní àṣáálẹ́ a máa pín ìkógun rẹ̀.” +Àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila ni a ti dárúkọ yìí, ati ohun tí baba wọn wí nígbà tí ó súre fún wọn. Ó súre tí ó tọ́ sí olukuluku fún un. +Jakọbu kìlọ̀ fún wọn, ó ní, “Mo ṣetán, mò ń re ibi àgbà á rè, inú ibojì tí wọ́n sin àwọn baba mi sí, ninu ihò òkúta tí ó wà ninu ilẹ̀ Efuroni, ará Hiti, ni kí ẹ sin mí sí. +Reubẹni, ìwọ ni àkọ́bí mi,agbára mi, ati àkọ́so èso agbára mi,ìwọ tí o ní ìgbéraga jùlọ,tí o sì lágbára jùlọ ninu àwọn ọmọ mi. +Ihò òkúta yìí wà ninu pápá ní Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure ní ilẹ̀ Kenaani. Lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti ni Abrahamu ti rà á pọ̀ mọ́ ilẹ̀ náà, kí ó lè rí ibi fi ṣe itẹ́ òkú. +Níbẹ̀ ni wọ́n sin Abrahamu ati Sara aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ náà ni wọ́n sin Isaaki sí ati Rebeka aya rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi náà sì sin Lea sí. +Lọ́wọ́ àwọn ará Hiti ni wọ́n ti ra ilẹ̀ náà ati ihò òkúta tí ó wà ninu rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ sin mí sí.” +Nígbà tí Jakọbu parí ìkìlọ̀ tí ó ń ṣe fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó ká ẹsẹ̀ rẹ̀ pada sí orí ibùsùn rẹ̀, ó dùbúlẹ̀, lẹ́yìn náà ó mí kanlẹ̀, ó sì re ibi tí àgbà á rè. +Ìwọ tí o dàbí ìkún omi tí ń bì síwá sẹ́yìn,o kò ní jẹ́ olórí, nítorí pé o ti bá obinrin mi lòpọ̀,o sì ti sọ ibùsùn èmi baba rẹ di aláìmọ́. +Simeoni ati Lefi jẹ́ arakunrin,ìlò ìkà ati ipá ni wọ́n ń lo idà wọn. +Orí mi má jẹ́ kí n bá wọn pa ìmọ̀ pọ̀,ẹlẹ́dàá mi má sì jẹ́ kí n bá wọn kẹ́gbẹ́.Nítorí wọn a máa fi ibinu paniyan,wọn a sì máa ṣá akọ mààlúù lọ́gbẹ́ bí ohun ìdárayá. +Ìfibú ni ibinu wọn, nítorí pé ó le,ati ìrúnú wọn, nítorí ìkà ni wọ́n.N óo pín wọn káàkiri ilẹ̀ Jakọbu,n óo sì fọ́n wọn ká ààrin àwọn eniyan Israẹli. +Juda, àwọn arakunrin rẹ yóo máa yìn ọ́,apá rẹ yóo sì ká àwọn ọ̀tá rẹ;àwọn ọmọ baba rẹ yóo máa tẹríba fún ọ. +Juda dàbí kinniun, tí ó bá pa ohun tí ó ń dọdẹ tán,a sì tún yan pada sinu ihò rẹ̀.Tí ó bá nà kalẹ̀, tí ó sì lúgọ,kò sí ẹni tí ó jẹ́ tọ́ ọ. +Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Jakọbu. +Àkọsílẹ̀ ìran Adamu nìyí: Nígbà tí Ọlọrun dá eniyan, ó dá wọn ní àwòrán ara rẹ̀. +Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé mẹẹdogun (815) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Gbogbo ọdún tí Enọṣi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé marun-un (905) kí ó tó kú. +Nígbà tí Kenani di ẹni aadọrin ọdún, ó bí Mahalaleli. +Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ogoji (840) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Gbogbo ọdún tí Kenani gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mẹ́wàá (910) kí ó tó kú. +Nígbà tí Mahalaleli di ẹni ọdún marundinlaadọrin, ó bí Jaredi. +Lẹ́yìn tí ó bí Jaredi, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Gbogbo ọdún tí Mahalaleli gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó dín marun-un (895) kí ó tó kú. +Nígbà tí Jaredi di ẹni ọdún mejilelọgọjọ (162) ó bí Enọku. +Lẹ́yìn tí ó bí Enọku, ó gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Takọ-tabo ni ó dá wọn, ó súre fún wọn, ó sì sọ wọ́n ní eniyan. +Gbogbo ọdún tí Jaredi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejilelọgọta (962) kí ó tó kú. +Nígbà tí Enọku di ẹni ọdún marundinlaadọrin ó bí Metusela. +Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun fún ọọdunrun (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Gbogbo ọdún tí Enọku gbé láyé jẹ́ ọọdunrun ọdún ó lé marundinlaadọrin (365). +Enọku wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun, nígbà tí ó yá, wọn kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun mú un lọ. +Nígbà tí Metusela di ẹni ọgọsan-an ọdún ó lé meje (187) ó bí Lamẹki. +Lẹ́yìn tí ó bí Lamẹki, ó gbé ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mejilelọgọrin (782) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Gbogbo ọdún tí Metusela gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mọkandinlaadọrin (969) kí ó tó kú. +Nígbà tí Lamẹki di ẹni ọdún mejilelọgọsan-an (182), ó bí ọmọkunrin kan. +Ó sọ ọ́ ní Noa, ó ní: “Eléyìí ni yóo mú ìtura wá fún wa ninu iṣẹ́ ati wahala wa tí à ń ṣe lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi gégùn-ún.” +Nígbà tí Adamu di ẹni aadoje (130) ọdún, ó bí ọmọkunrin kan. Ọmọ náà jọ ọ́ gidigidi, bí Adamu ti rí gan-an ni ọmọ náà rí. Ó bá sọ ọ́ ní Seti. +Lẹ́yìn tí Lamẹki bí Noa, ó gbé ọdún marundinlẹgbẹta (595) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Gbogbo ọdún tí Lamẹki gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mẹtadinlọgọrin (777) kí ó tó kú. +Nígbà tí Noa di ẹni ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún, ó bí Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. +Lẹ́yìn tí ó bí Seti, ó tún gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Gbogbo ọdún tí Adamu gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), kí ó tó kú. +Nígbà tí Seti di ẹni ọdún marundinlaadọfa (105), ó bí Enọṣi. +Lẹ́yìn tí ó bí Enọṣi, ó tún gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé meje (807) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. +Gbogbo ọdún tí Seti gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejila (912), kí ó tó kú. +Nígbà tí Enọṣi di ẹni aadọrun-un ọdún, ó bí Kenani. +Ìwé Àkọsílẹ̀ Ìran Adamu. +Josẹfu dojúbo òkú baba rẹ̀ lójú, ó sọkún, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. +Nígbà tí wọ́n dé ibi ìpakà Atadi, níwájú Jọdani, wọ́n pohùnréré ẹkún, Josẹfu sì ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ meje. +Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ibẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ ní ibi ìpakà náà, wọ́n wí pé, “Òkú yìí mà kúkú dun àwọn ará Ijipti o!” Nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Abeli Misiraimu, ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani. +Àwọn ọmọ Jakọbu sin òkú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún wọn. +Wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì sin ín sinu ihò òkúta tí ó wà ninu oko Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure, tí Abrahamu rà mọ́ ilẹ̀ tí ó rà lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti láti fi ṣe itẹ́ òkú. +Nígbà tí Josẹfu sin òkú baba rẹ̀ tán, ó pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n bá a lọ. +Nígbà tí àwọn arakunrin Josẹfu rí i pé baba àwọn ti kú, wọ́n ní, “Ó ṣeéṣe kí Josẹfu kórìíra wa, kí ó sì gbẹ̀san gbogbo ibi tí a ti ṣe sí i.” +Wọ́n bá ranṣẹ sí Josẹfu pé, “Baba rẹ ti fi àṣẹ yìí lélẹ̀ kí ó tó kú pé, +‘Ẹ sọ fún Josẹfu pé, dárí àṣìṣe ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn arakunrin rẹ jì wọ́n, nítorí wọ́n ṣe ibi sí ọ.’ ” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí Josẹfu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó bú sẹ́kún. +Àwọn arakunrin rẹ̀ náà sì wá, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ní, “Wò ó, a di ẹrú rẹ.” +Ṣugbọn Josẹfu wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, èmi kì í ṣe Ọlọrun. +Lẹ́yìn náà, Josẹfu pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọn ń ṣiṣẹ́ ìṣègùn pé kí wọ́n fi òògùn tí wọ́n fi máa ń tọ́jú òkú, tí kì í fíí bàjẹ́, tọ́jú òkú baba òun. Wọ́n fi òògùn yìí tọ́jú òkú Jakọbu. +Ní tiyín, ẹ gbèrò ibi sí mi, ṣugbọn Ọlọrun yí i pada sí rere, kí ó lè dá ẹ̀mí ọpọlọpọ eniyan tí wọ́n wà láàyè lónìí sí. +Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù, n óo máa tọ́jú ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn, tí ó sì dá wọn lọ́kànle. +Josẹfu sì ń gbé ilẹ̀ Ijipti, òun ati ìdílé baba rẹ̀, ó gbé aadọfa (110) ọdún láyé. +Josẹfu rí ìran kẹta ninu àwọn ọmọ Efuraimu. Àwọn ọmọ tí Makiri ọmọ Manase bí, ọwọ́ Josẹfu ni ó bí wọn sí pẹlu. +Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé, “Àtikú mi kù sí dẹ̀dẹ̀, ṣugbọn Ọlọrun yóo máa tọ́jú yín, yóo sì mu yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí, lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu.” +Josẹfu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra fún un pé, nígbà tí Ọlọrun bá mú wọn pada sí ilẹ̀ Kenaani, wọn yóo kó egungun òun lọ́wọ́ lọ. +Josẹfu kú nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. Wọ́n fi òògùn tọ́jú òkú rẹ̀ kí ó má baà bàjẹ́, wọ́n sì tẹ́ ẹ sinu pósí ní ilẹ̀ Ijipti. +Ogoji ọjọ́ gbáko ni àwọn oníṣègùn máa fi ń tọ́jú irú òkú bẹ́ẹ̀. Àwọn ará Ijipti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún aadọrin ọjọ́. +Nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, Josẹfu sọ fún àwọn ará ilé Farao pé, “Ẹ jọ̀wọ́, bí inú yín bá dùn sí mi, ẹ bá mi sọ fún Farao pé, +baba mi mú mi búra nígbà tí àtikú rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, pé, ‘Nígbà tí mo bá kú, ninu ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kenaani, ni kí ẹ sin mí sí.’ Nítorí náà, kí Farao jọ̀wọ́, fún mi láàyè kí n lọ sin òkú baba mi, n óo sì tún pada wá.” +Farao dáhùn, ó ní, “Lọ sin òkú baba rẹ gẹ́gẹ́ bí o ti búra fún un.” +Josẹfu lọ sin òkú baba rẹ̀, gbogbo àwọn iranṣẹ Farao sì bá a lọ, ati gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà ààfin ọba, ati gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú Ijipti, +ati gbogbo ìdílé Josẹfu àwọn arakunrin rẹ̀ ati ìdílé baba rẹ̀, àfi àwọn ọmọde, àwọn agbo ẹran, ati àwọn mààlúù nìkan ni ó kù sí ilẹ̀ Goṣeni. +Kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin bá a lọ pẹlu, àwọn eniyan náà pọ̀ lọpọlọpọ. +Josẹfu tún Dá Àwọn Arakunrin Rẹ̀ Lọ́kànle. +Nígbà tí eniyan bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i lórí ilẹ̀, tí wọ́n sì ń bí ọmọbinrin, +Ó bí ọmọkunrin mẹta tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti. +Ayé kún fún ìwà ìbàjẹ́ lójú Ọlọrun, ìwà jàgídíjàgan sì gba gbogbo ayé. +Ọlọrun rí i pé ayé ti bàjẹ́, nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo eniyan ń hù. +Ọlọrun bá sọ fún Noa pé, “Mo ti pinnu láti pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, nítorí ìwà ipá wọn ti gba gbogbo ayé, àtàwọn àtayé ni n óo parun. +Nítorí náà, fi igi goferi kan ọkọ̀ ojú omi fún ara rẹ. Ṣe ọpọlọpọ yàrá sinu rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà kùn ún ninu ati lóde. +Bí o óo ti kan ọkọ̀ náà nìyí: kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọọdunrun (300) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. +Kan òrùlé sí orí ọkọ̀ náà, ṣugbọn fi ààyè sílẹ̀ láàrin orí rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, tí yóo jẹ́ ìwọ̀n igbọnwọ kan. Kí o kan ọkọ̀ náà ní ìpele mẹta, kí o sì ṣe ẹnu ọ̀nà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. +N óo jẹ́ kí ìkún omi bo gbogbo ayé, yóo pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà láyé ni yóo kú. +Ṣugbọn n óo bá ọ dá majẹmu, o óo wọ inú ọkọ̀ náà, ìwọ pẹlu aya rẹ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn aya wọn. +Kí o sì mú meji meji ninu gbogbo ohun alààyè, kí wọ́n lè wà láàyè pẹlu rẹ, takọ-tabo ni kí o mú wọn. +nígbà náà ni àwọn ẹ̀dá ọ̀run lọkunrin ṣe akiyesi pé àwọn ọmọbinrin tí eniyan ń bí lẹ́wà gidigidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ èyí tí ó wù wọ́n lára wọn. +Meji meji yóo tọ̀ ọ́ wá ninu oríṣìíríṣìí àwọn ẹyẹ, ati oríṣìíríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn, ati oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí o lè mú kí wọ́n wà láàyè pẹlu rẹ. +Kí o sì kó oniruuru oúnjẹ sinu ọkọ̀ náà fún ara rẹ ati fún wọn.” +Noa bá ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun pàṣẹ fún un. +OLUWA bá wí pé, “N kò ní jẹ́ kí eniyan wà láàyè títí lae, nítorí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n. Ọgọfa (120) ọdún ni wọn yóo máa gbé láyé.” +Àwọn òmìrán wà láyé ní ayé ìgbà náà, wọ́n tilẹ̀ tún wà láyé fún àkókò kan lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin Ọlọrun fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ eniyan, àwọn ọmọ tí wọ́n bí ni àwọn òmìrán wọnyi. Àwọn ni wọ́n jẹ́ akọni ati olókìkí nígbà náà. +Nígbà tí OLUWA rí i pé ìwà burúkú eniyan ti pọ̀ jù láyé, ati pé kìkì ibi ni èrò inú wọn nígbà gbogbo, +inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi pé ó dá eniyan sí ayé, ó sì dùn ún, +tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “N óo pa àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo dá run lórí ilẹ̀ ayé, ati eniyan ati ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati ẹyẹ, gbogbo wọn ni n óo parun, nítorí ó bà mí ninu jẹ́ pé mo dá wọn.” +Ṣugbọn Noa rí ojurere OLUWA. +Ìtàn ìran Noa nìyí: Noa jẹ́ olódodo, òun nìkan ṣoṣo ni eniyan pípé ní àkókò tirẹ̀, ó sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu OLUWA. +Ìwà Burúkú Eniyan. +Nígbà tí ó yá OLUWA sọ fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ, nítorí pé ìwọ nìkan ni o jẹ́ olódodo sí mi ní gbogbo ayé. +Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi bo ilẹ̀ ayé. +Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keji ọdún tí Noa di ẹni ẹgbẹta (600) ọdún, ni orísun alagbalúgbú omi tí ó wà ninu ọ̀gbun ńlá lábẹ́ ilẹ̀ ya, tí gbogbo fèrèsé omi tí ó wà ní ojú ọ̀run ṣí sílẹ̀, +òjò sì rọ̀ fún ogoji ọjọ́, tọ̀sán-tòru. +Ní ọjọ́ náà gan-an ni Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti ati aya rẹ̀ ati àwọn aya àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta; +pẹlu àwọn ẹranko ati àwọn ẹran ọ̀sìn, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati oniruuru àwọn ẹyẹ. +Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè patapata ni wọ́n wọ inú ọkọ̀ tọ Noa lọ ní meji meji. +Gbogbo àwọn ohun ẹlẹ́mìí, akọ kan, abo kan, ní oríṣìí kọ̀ọ̀kan wọlé gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Noa. OLUWA bá ti ìlẹ̀kùn ọkọ̀ náà. +Ìkún omi wà lórí ilẹ̀ fún ogoji ọjọ́. Omi náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi léfòó lójú omi. +Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i ni ọkọ̀ náà ń lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún lórí rẹ̀. +Omi náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi bo gbogbo àwọn òkè gíga tí wọ́n wà láyé mọ́lẹ̀. +Ninu gbogbo ẹran tí ó bá jẹ́ mímọ́, mú wọn ní takọ-tabo, meje meje, ṣugbọn ninu gbogbo ẹran tí kò bá jẹ́ mímọ́, mú akọ kan ati abo kan. +Ó sì tún pọ̀ sí i títí tí ó fi ga ju àwọn òkè gíga lọ ní igbọnwọ mẹẹdogun (mita 7). +Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé ni wọ́n kú patapata, ati ẹyẹ, ati ẹran ọ̀sìn, ati ẹranko, ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà ati eniyan. +Gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń mí lórí ilẹ̀ ayé patapata ni wọ́n kú. +Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe pa gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé run: gbogbo eniyan, gbogbo ẹranko, gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ati ẹyẹ. Noa nìkan ni kò kú ati àwọn tí wọ́n jọ wà ninu ọkọ̀ pẹlu rẹ̀. +Aadọjọ (150) ọjọ́ gbáko ni omi fi bo gbogbo ilẹ̀. +Mú takọ-tabo meje meje ninu àwọn ẹyẹ, kí irú wọn lè wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé. +Nítorí pé ọjọ́ meje ló kù tí n óo bẹ̀rẹ̀ sí rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí mo dá ni yóo sì parun lórí ilẹ̀ ayé.” +Noa bá ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un. +Noa jẹ́ ẹni ẹgbẹta (600) ọdún nígbà tí ìkún omi bo ilẹ̀ ayé. +Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati aya rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu aya wọn, láti sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìkún omi. +Gbogbo ẹran ati àwọn tí wọ́n mọ́ ati àwọn tí wọn kò mọ́, àwọn ẹyẹ ati gbogbo ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, +ní meji meji, àtakọ àtabo, gbogbo wọn bá Noa wọ inú ọkọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún Noa. +Ìkún Omi. +Ṣugbọn Ọlọrun ranti Noa, ati gbogbo ẹranko, ati ẹran ọ̀sìn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀. Nítorí náà, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ kan f��̣ sórí ilẹ̀, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fà. +Ó dúró fún ọjọ́ meje kí ó tó tún rán àdàbà náà jáde. +Àdàbà náà fò pada ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà pẹlu ewé olifi tútù ní ẹnu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Noa ṣe mọ̀ pé omi ti fà lórí ilẹ̀. +Ó tún dúró fún ọjọ́ meje sí i, lẹ́yìn náà, ó tún rán àdàbà náà jáde, ṣugbọn àdàbà náà kò pada sọ́dọ̀ Noa mọ́. +Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni ọdún tí Noa di ẹni ọdún mọkanlelẹgbẹta (601), omi gbẹ tán lórí ilẹ̀. Noa ṣí òrùlé ọkọ̀, ó yọjú wo ìta, ó sì rí i pé ilẹ̀ ti gbẹ. +Ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù keji ni ilẹ̀ gbẹ tán patapata. +Ọlọrun sọ fún Noa pé, +“Jáde kúrò ninu ọkọ̀, ìwọ ati aya rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn aya wọn. +Kó gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹlu rẹ jáde, àwọn ẹyẹ, ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí wọ́n lè máa bímọ lémọ, kí wọ́n sì pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé.” +Noa bá jáde kúrò ninu ọkọ̀, òun ati aya rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn aya wọn, +pẹlu gbogbo àwọn ẹranko, gbogbo àwọn ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ati àwọn ẹyẹ. Gbogbo àwọn ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ patapata ni wọ́n bá Noa jáde kúrò ninu ọkọ̀. +Ọlọrun sé orísun omi tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀, ó ti àwọn fèrèsé ojú ọ̀run, òjò náà sì dá. +Noa tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA, ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹran ati àwọn ẹyẹ tí wọ́n mọ́, ó fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ náà. +Nígbà tí OLUWA gbọ́ òórùn dídùn ẹbọ náà, ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “N kò ní fi ilẹ̀ gégùn-ún mọ́ nítorí eniyan, nítorí pé, láti ìgbà èwe wọn wá ni èrò inú wọn ti jẹ́ kìkì ibi. Bẹ́ẹ̀ ni n kò ní pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run mọ́ bí mo ti ṣe yìí. +Níwọ̀n ìgbà tí ayé bá ṣì wà, ìgbà gbígbìn ati ìgbà ìkórè kò ní ṣàìwà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbà òtútù ati ìgbà ooru, ìgbà òjò ati ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yóo sì máa wà pẹlu.” +Omi bá bẹ̀rẹ̀ sí fà lórí ilẹ̀. Lẹ́yìn aadọjọ (150) ọjọ́, omi náà fà tán. +Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keje, ìdí ọkọ̀ náà kanlẹ̀ lórí òkè Ararati. +Omi náà sì ń fà sí i títí di oṣù kẹwaa. Ní ọjọ́ kinni oṣù náà ni ṣóńṣó orí àwọn òkè ńlá hàn síta. +Lẹ́yìn ogoji ọjọ́, Noa ṣí fèrèsé ọkọ̀ tí ó kàn. +Ó rán ẹyẹ ìwò kan jáde. Ẹyẹ yìí bẹ̀rẹ̀ sí fò káàkiri títí tí omi fi gbẹ lórí ilẹ̀. +Ó tún rán ẹyẹ àdàbà kan jáde láti lọ wò ó bóyá omi ti gbẹ lórí ilẹ̀, +ṣugbọn àdàbà náà kò rí ibi tí ó lè bà sí nítorí pé omi bo gbogbo ilẹ̀, ó bá fò pada tọ Noa lọ ninu ọkọ̀. Noa na ọwọ́ jáde láti inú ọkọ̀, ó sì mú un wọlé. +Ìkún Omi Gbẹ. +Ọlọrun súre fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé. +Gbogbo àwọn ẹyẹ, àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko tí wọ́n bá yín jáde ninu ọkọ̀, +majẹmu náà ni pé, lae, n kò tún ní fi ìkún omi pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ìkún omi tí yóo pa ayé rẹ́ mọ́. +Ohun tí yóo jẹ́ àmì majẹmu tí mo ń bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá, tí yóo sì wà fún atọmọdọmọ yín ní ọjọ́ iwájú nìyí: +mo fi òṣùmàrè mi sí ojú ọ̀run, òun ni yóo máa jẹ́ àmì majẹmu tí mo bá ayé dá. +Nígbàkúùgbà tí mo bá mú kí òjò ṣú ní ojú ọ̀run, tí òṣùmàrè bá sì yọ jáde, +n óo ranti majẹmu tí mo bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá pé, omi kò ní kún débi pé yóo pa ayé rẹ́ mọ́. +Nígbà tí òṣùmàrè bá yọ, n óo wò ó, n óo sì ranti majẹmu ayérayé tí èmi Ọlọrun bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá. +Èyí ni majẹmu tí mo bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.” +Àwọn ọmọ Noa tí wọ́n jáde ninu ọkọ̀ ni: Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Hamu ni ó bí Kenaani. +Àwọn ọmọ Noa mẹtẹẹta yìí ni baba ńlá gbogbo ayé. +Gbogbo ẹranko tí ó wà láyé, gbogbo ẹyẹ, gbogbo ẹja tí ń bẹ ninu omi, ati gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri ni yóo máa bẹ̀rù yín, ìkáwọ́ yín ni mo fi gbogbo wọn sí. +Noa ni ẹni kinni tí ó kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀, tí ó gbin ọgbà àjàrà. +Noa mu àmupara ninu ọtí waini ọgbà rẹ̀, ó sì sùn sinu àgọ́ rẹ̀ ní ìhòòhò. +Hamu, baba Kenaani, rí baba rẹ̀ ní ìhòòhò, ó lọ sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ mejeeji lóde. +Ṣemu ati Jafẹti bá mú aṣọ kan, wọ́n fà á kọ́ èjìká wọn, wọ́n fi ẹ̀yìn rìn lọ sí ibi tí baba wọn sùn sí, wọ́n sì dà á bò ó, wọ́n kọ ojú sí ẹ̀gbẹ́ kan, wọn kò sì rí ìhòòhò baba wọn. +Nígbà tí ọtí dá lójú Noa, tí ó gbọ́ ohun tí àbíkẹ́yìn rẹ̀ ṣe sí i, +Ó ní,“Ẹni ègún ni Kenaani,ẹrú lásánlàsàn ni yóo jẹ́ fún àwọn arakunrin rẹ̀.” +Ó tún fi kún un pé,“Kí OLUWA Ọlọrun mi bukun Ṣemu,ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe. +Kí Ọlọrun sọ ìdílé Jafẹti di pupọ,kí ó máa gbé ninu àgọ́ Ṣemu,ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe.” +Ọọdunrun ọdún ó lé aadọta (350) ni Noa tún gbé sí i lẹ́yìn ìkún omi. +Noa kú nígbà tí ó di ẹni ẹgbẹrun ọdún ó dín aadọta (950). +Gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ni yóo jẹ́ oúnjẹ fún yín, bí mo ti fún yín ní gbogbo ewéko, bẹ́ẹ̀ náà ni mo fún yín ní ohun gbogbo. +Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ti òun ti ẹ̀jẹ̀, nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ìyè wà. +Dájúdájú n óo gbẹ̀san lára ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, kì báà jẹ́ ẹranko ni ó paniyan tabi eniyan ni ó pa ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, pípa ni a óo pa olúwarẹ̀. +Ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, pípa ni a óo pa òun náà, nítorí pé ní àwòrán Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó dá eniyan. +“Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.” +Lẹ́yìn náà Ọlọrun sọ fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, +“Wò ó! Mo bá ẹ̀yin ati atọmọdọmọ yín dá majẹmu, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè tí wọ́n wà pẹlu yín: +Ọlọrun Bá Noa Dá Majẹmu. +Ìran tí Ọlọrun fihan wolii Habakuku nìyí. +Wọn a máa fi àwọn ọba ṣe ẹlẹ́yà, wọn a sì sọ àwọn ìjòyè di àmúṣèranwò. Wọn a máa fi àwọn ìlú olódi ṣe ẹlẹ́yà, nítorí òkítì ni wọ́n mọ sí ara odi wọn, wọn a sì gbà wọ́n. +Wọn a fẹ́ wá bí ìjì, wọn a sì tún fẹ́ lọ, àwọn olubi eniyan, tí agbára wọn jẹ́ ọlọrun wọn.” +OLUWA, ṣebí láti ayérayé ni o ti wà? Ọlọrun mi, Ẹni Mímọ́ mi, a kò ní kú. OLUWA, ìwọ ni o yan àwọn ará Babiloni gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́. Ìwọ Àpáta, ni o gbé wọn kalẹ̀ bíi pàṣán, láti jẹ wá níyà. +Mímọ́ ni ojú rẹ, o kò lè wo ibi o kò lè gba ohun tí kò tọ́. Kí ló wá dé tí o fi ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀, tí o sì dákẹ́, tí ò ń wo àwọn ẹni ibi níran tí wọn ń run àwọn tí wọ́n ṣe olódodo jù wọ́n lọ. +Nítorí o ti jẹ́ kí ọmọ eniyan dàbí ẹja inú òkun, ati bí àwọn kòkòrò tí wọn ń rìn nílẹ̀, tí wọn kò ní olórí. +Ọ̀tá fi ìwọ̀ fa gbogbo wọn sókè, ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ kó wọn jáde. Ó kó wọn papọ̀ sinu àwọ̀n rẹ̀, Nítorí náà ó ń yọ̀, inú rẹ̀ sì dùn. +Nítorí náà a máa bọ àwọ̀n rẹ̀. A sì máa fi turari rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀ ńlá; nítorí a máa rò lọ́kàn rẹ̀ pé, àwọ̀n òun ni ó ń jẹ́ kí òun gbádùn ayé tí òun sì fi ń rí oúnjẹ aládùn jẹ. +Ṣé gbogbo ìgbà ni àwọn eniyan yóo máa bọ́ sinu àwọ̀n rẹ̀ ni? Ṣé títí lae ni yóo sì máa pa àwọn orílẹ̀-èdè run láìláàánú? +OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí n óo máa ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́; tí o kò sì ní dá mi lóhùn? Tí n óo máa ké pé, “Wo ìwà ipá!” tí o kò sì ní gba olúwarẹ̀ sílẹ̀? +Kí ló dé tí o fi ń jẹ́ kí n máa rí àwọn nǹkan tí kò tọ́, tí o jẹ́ kí n máa rí ìyọnu? Ìparun ati ìwà ipá wà níwájú mi, ìjà ati aáwọ̀ sì wà níbi gbogbo. +Òfin kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́ òdodo. Àwọn ẹni ibi dòòyì ká olódodo, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ òdodo po. +Ọlọrun ní: “Wo ààrin àwọn orílẹ̀-èdè yíká, O óo rí ohun ìjọjú yóo sì yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí mò ń ṣe nǹkan ìyanu kan ní àkókò rẹ, tí o kò ní gbàgbọ́ bí wọ́n bá sọ fún ọ. +Wò ó! N óo gbé àwọn ará Kalidea dìde, orílẹ̀-èdè tí ó yára, tí kò sì ní àánú; àwọn tí wọ́n la ìbú ayé já, tí wọn ń gba ilẹ̀ onílẹ̀ káàkiri. +Ìrísí wọn bani lẹ́rù; wọ́n ń fi ọlá ńlá wọn ṣe ìdájọ́ bí ó ti wù wọ́n. +“Àwọn ẹṣin wọn yára ju àmọ̀tẹ́kùn lọ, wọ́n burú ju ìkookò tí ebi ń pa ní àṣáálẹ́ lọ. Pẹlu ìgbéraga ni àwọn ẹlẹ́ṣin wọn máa ń gun ẹṣin wọn lọ. Dájúdájú, ọ̀nà jíjìn ni àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ti ń wá; wọn a fò, bí idì tí ń sáré sí oúnjẹ. +“Tìjàtìjà ni gbogbo wọn máa ń rìn, ìpayà á bá gbogbo eniyan bí wọ́n bá ti ń súnmọ́ tòsí. Wọn a kó eniyan ní ìgbèkùn, bí ẹni kó yanrìn nílẹ̀. +Ìráhùn Habakuku sí Ọlọrun. +N óo dúró sí ibìkan lórí ilé-ìṣọ́, n óo máa wòran. N óo dúró, n óo máa retí ohun tí yóo sọ fún mi, ati irú èsì tí èmi náà óo fún un. +O ti kó ìtìjú bá ilé rẹ nítorí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè tí o parun; ìwọ náà ti wá pàdánù ẹ̀mí rẹ. +Nítorí òkúta yóo kígbe lára ògiri, igi ìdábùú òpó ilé yóo sì fọhùn pẹlu. +Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ìwà ìpànìyàn kó ìlú jọ, tí ẹ fi ìwà ọ̀daràn tẹ ìlú dó. +Wò ó, ṣebí ìkáwọ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó wà, pé kí orílẹ̀-èdè kan ṣe làálàá tán, kí iná sì jó gbogbo rẹ̀ ní àjórun, kí wahala orílẹ̀-èdè náà sì já sí asán. +Nítorí ayé yóo kún fún ìmọ̀ ògo OLUWA, gẹ́gẹ́ bí omi ti kún inú òkun. +Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ fi ibinu fún aládùúgbò yín ní ọtí mu, tí ẹ jẹ́ kí inú wọn ru, kí ẹ lè rí ìhòòhò wọn. +Ìtìjú ni yóo bò yín dípò ògo. Ẹ máa mu àmupara kí ẹ sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, ife ìjẹníyà tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún OLUWA yóo kàn yín, ìtìjú yóo sì bo ògo yín. +Ibi tí ó dé bá Lẹbanoni yóo bò yín mọ́lẹ̀; ìparun àwọn ẹranko yóo dẹ́rùbà yín, nítorí ìpànìyàn ati ibi tí ẹ ṣe sí ayé, sí àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn. +Èrè kí ni ó wà ninu ère? Ère irin lásánlàsàn, tí eniyan ṣe, tí ń kọ́ni ní irọ́ pípa. Nítorí ẹni tí ó ṣe wọ́n gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ère tí ó gbẹ́ tán tí kò lè sọ̀rọ̀! +Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún ohun tí a fi igi gbẹ́, pé kí ó dìde; ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún òkúta tí kò lè sọ̀rọ̀, pé kí ó gbéra nílẹ̀. Ǹjẹ́ eléyìí lè rí ìran kankan? Wò ó! Wúrà ati fadaka ni wọ́n yọ́ lé e, kò sì ní èémí ninu rárá. +OLUWA dá mi lóhùn, ó ní: “Kọ ìran yìí sílẹ̀; kọ ọ́ sórí tabili kí ó hàn ketekete, kí ó lè rọrùn fún ẹni tí ń sáré lọ láti kà á. +Ṣugbọn OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀, kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ̀. +Kọ ọ́ sílẹ̀, nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú ni; ọjọ́ náà kò ní pẹ́ dé, ohun tí o rí kì í ṣe irọ́, dájúdájú yóo ṣẹ. Bí ó bá dàbí ẹni pé ó ń pẹ́, ìwọ ṣá dúró kí o máa retí rẹ̀, dájúdájú, yóo ṣẹ, láìpẹ́. +Wò ó! Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò ṣe déédéé ninu OLUWA yóo ṣègbé; ṣugbọn olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.” +Ọrọ̀ a máa tan eniyan jẹ; onigbeeraga kò sì ní wà láàyè pẹ́. Ojúkòkòrò rẹ̀ dàbí isà òkú; nǹkan kì í sì í tó o, àfi bí ikú. Ó gbá gbogbo orílẹ̀-èdè jọ fún ara rẹ̀, ó sì sọ gbogbo eniyan di ti ara rẹ̀. +Ǹjẹ́ gbogbo àwọn eniyan wọnyi kò ní máa kẹ́gàn rẹ̀, kí wọ́n sì máa fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ń kó ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ jọ. Ìgbà wo ni yóo ṣe èyí dà, tí yóo máa gba ìdógò lọ́wọ́ àwọn onígbèsè rẹ̀ kiri?” +Ǹjẹ́ àwọn onígbèsè rẹ kò ní dìde sí ọ lójijì, kí àwọn tí wọn yóo dẹ́rùbà ọ́ sì jí dìde, kí o wá di ìkógun fún wọn? +Nítorí pé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni o ti kó lẹ́rú, gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọn yóo sì kó ìwọ náà lẹ́rú, nítorí ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan tí o ti pa, ati ìwà ipá tí o hù lórí ilẹ̀ ayé, ati èyí tí o hù sí oríṣìíríṣìí ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn. +Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ipá kó èrè burúkú jọ tí ẹ óo fi kọ́ ibùgbé sí ibi gíga, kí nǹkan burúkú kankan má baà ṣẹlẹ̀ si yín! +Ìdáhùn OLUWA sí Habakuku. +Adura tí wolii Habakuku kọ lórin nìyí: +Nígbà tí àwọn òkè ńlá rí ọ,wọ́n wárìrì;àgbàrá omi wọ́ kọjá;ibú òkun pariwo,ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè. +Oòrùn ati òṣùpá dúró ní ipò wọn,nígbà tí ọfà rẹ ń já lọ ṣòòrò,tí àwọn ọ̀kọ̀ rẹ náà ń kọ mànà,bí wọ́n ti ń fò lọ. +O la ayé kọjá pẹlu ibinu,o sì fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀. +O jáde lọ láti gba àwọn eniyan rẹ là,láti gba àwọn àyànfẹ́ rẹ là.O wó orí aṣiwaju ilẹ̀ àwọn ẹni ibi wómúwómú,o tú u sí ìhòòhò láti itan dé ọrùn. +O fi ọ̀kọ̀ rẹ gún orí àwọn olórí ogun;àwọn tí wọ́n wá bí ìjì líleláti tú wa ká,tí wọn ń yọ̀ bí ẹni tí ń ni talaka lára níkọ̀kọ̀. +O fi àwọn ẹṣin rẹ tẹ òkun mọ́lẹ̀;wọ́n tẹ ríru omi mọ́lẹ̀. +Mo gbọ́, àyà mi sì lù kìkì,ètè mi gbọ̀n pẹ̀pẹ̀nígbà tí mo gbọ́ ìró rẹ̀;egungun mi bẹ̀rẹ̀ sí rà,ẹsẹ̀ mi ń gbọ̀n rìrì nílẹ̀.N óo fi sùúrù dúró jẹ́ẹ́ de ọjọ́ tí ìṣòro yóo débá àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù. +Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ kò tilẹ̀ rúwé,tí àjàrà kò sì so,tí kò sí èso lórí igi olifi;tí àwọn irúgbìn kò sì so lóko,tí àwọn agbo aguntan run,tí kò sì sí mààlúù ninu agbo mọ́, +sibẹsibẹ, n óo yọ̀ ninu OLUWA,n óo yọ̀ ninu Ọlọrun Olùgbàlà mi. +Ọlọrun, OLUWA, ni agbára mi;Ó mú kí ẹsẹ̀ mi yá nílẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín,ó mú mi rìn l��rí àwọn òkè gíga. (Sí ọ̀gá akọrin; pẹlu àwọn ohun èlò orin olókùn.) +OLUWA, mo ti gbọ́ òkìkí rẹ,mo sì bẹ̀rù iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.Gbogbo bí ò ó tíí ṣe tí à ń gbọ́;tún wá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tiwa;sì ranti àánú ní àkókò ibinu rẹ. +OLUWA wá láti Temani,Ẹni Mímọ́ sì wá láti òkè Parani.Ògo rẹ̀ bo ojú ọ̀run,gbogbo ayé sì kún fún ìyìn rẹ̀. +Dídán rẹ̀ dàbí ọ̀sán gangan,ìtànṣán ń ti ọwọ́ rẹ̀ jáde;níbẹ̀ ni ó fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí. +Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ níwájú rẹ̀,ìyọnu sì ń tẹ̀lé e lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí. +Ó dúró, ó wọn ayé;Ó wo ayé, ó sì mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì;àwọn òkè ńláńlá ayérayé túká,àwọn òkè àtayébáyé sì wọlẹ̀.Ọ̀nà àtayébáyé ni ọ̀nà rẹ̀. +Mo rí àwọn àgọ́ Kuṣani ninu ìyọnu,àwọn aṣọ ìkélé àwọn ará ilẹ̀ Midiani sì ń mì tìtì. +OLUWA, ṣé àwọn odò ni inú rẹ ń ru sí ni,àbí àwọn ìṣàn omi ni ò ń bínú sí,tabi òkun ni ò ń bá bínú,nígbà tí o bá gun àwọn ẹṣin rẹ,tí o wà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ? +Ìwọ tí ò ń tu àkọ̀ kúrò lára ọrun,tí o fi ọfà lé ọsán ọrun;tí o wá fi omi pín ilẹ̀ ayé. +Adura Habakuku. +Ní ọjọ́ kinni, oṣù kẹfa, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA rán wolii Hagai sí Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati sí Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa. +Ìdí nìyí tí ìrì kò fi sẹ̀ láti òkè ọ̀run wá, tí ilẹ̀ kò sì fi so èso bí ó ti yẹ. +Mo mú ọ̀gbẹlẹ̀ wá sórí ilẹ̀, ati sórí àwọn òkè, ati oko ọkà, ati ọgbà àjàrà ati ọgbà igi olifi. Bẹ́ẹ̀ náà ló kan gbogbo ohun tí ń hù lórí ilẹ̀, ati eniyan ati ẹran ọ̀sìn, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ eniyan.” +Ni Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli ati Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa, ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù bá gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun wọn lẹ́nu, wọ́n fetí sí ọ̀rọ̀ wolii Hagai, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wọn ti rán an; wọ́n sì bẹ̀rù OLUWA. +Ni Hagai, òjíṣẹ́ OLUWA, bá jẹ́ iṣẹ́ tí OLUWA rán an sí àwọn eniyan náà pé òun OLUWA ní òun wà pẹlu wọn. +OLUWA bá fi ìtara rẹ̀ sí ọkàn Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati sí ọkàn Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa ati ọkàn gbogbo àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wọn. +Ọjọ́ kẹrinlelogun, oṣù kẹfa, ọdún keji ìjọba Dariusi, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà. +OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Àwọn eniyan wọnyi ní, kò tíì tó àkókò láti tún Tẹmpili kọ́.” +Nítorí náà ni OLUWA ṣe rán wolii Hagai sí wọn ó ní, +“Ẹ̀yin eniyan mi, ṣé àkókò nìyí láti máa gbé inú ilé tiyín tí ẹ ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, nígbà tí Tẹmpili wà ní àlàpà? +Nítorí náà, nisinsinyii, ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín: +Ohun ọ̀gbìn pupọ ni ẹ gbìn, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ kórè; ẹ jẹun, ṣugbọn ẹ kò yó; ẹ mu, ṣugbọn kò tẹ yín lọ́rùn; ẹ wọṣọ, sibẹ òtútù tún ń mu yín. Àwọn tí wọn ń gba owó iṣẹ́ wọn, inú ajádìí-àpò ni wọ́n ń gbà á sí. +Ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Ẹ lọ sórí àwọn òkè, kí ẹ gé igi ìrólé láti kọ́ ilé náà, kí inú mi lè dùn sí i, kí n sì lè farahàn ninu ògo mi. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí. +“Ẹ̀ ń retí ọ̀pọ̀ ìkórè, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ̀ ń rí; nígbà tí ẹ sì mú díẹ̀ náà wálé, èmi á gbọ̀n ọ́n dànù. Mò ń bi yín, ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ó fà á? Ìdí rẹ̀ ni pé, ẹ fi ilé mi sílẹ̀ ní òkítì àlàpà, olukuluku sì múra sí kíkọ́ ilé tirẹ̀. +OLUWA pàṣẹ láti tún Tẹmpili Kọ́. +Ní ọjọ́ kọkanlelogun oṣù keje, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA tún sọ fún wolii Hagai, pé: +Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, ní ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA sọ fún wolii Hagai pé, +“Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo ní kí o lọ bèèrè ìdáhùn lórí ọ̀rọ̀ yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa. +Ǹjẹ́ bí ẹnìkan bá mú ẹran tí a fi rúbọ, tí ó ti di mímọ́, tí ó dì í mọ́ ìṣẹ́tí ẹ̀wù rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀wù náà kan burẹdi, tabi àsáró, tabi waini, tabi òróró, tabi oúnjẹ-kóúnjẹ, ṣé ọ̀kan kan ninu àwọn oúnjẹ yìí lè tipa bẹ́ẹ̀ di mímọ́?” Àwọn alufaa bá dáhùn pé, “Rárá.” +Nígbà náà ni Hagai tún bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ bí ẹnìkan bá di aláìmọ́ nítorí pé ó farakan òkú, tí ó sì fọwọ́ kan ọ̀kan ninu àwọn ohun tí a kà sílẹ̀ wọnyi ǹjẹ́ kò ní di aláìmọ́?” Wọ́n dáhùn pé: “Dájúdájú, yóo di aláìmọ́.�� +Hagai bá dáhùn, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí fún àwọn eniyan wọnyi ati fún orílẹ̀-èdè yìí pẹlu iṣẹ́ ọwọ́ wọn níwájú OLUWA; gbogbo ohun tí wọ́n fi ń rúbọ jẹ́ aláìmọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA wí. +OLUWA ní, “Nisinsinyii, ẹ kíyèsí ohun tí yóo máa ṣẹlẹ̀ láti àkókò yìí lọ. Ẹ ranti bí ó ti rí fun yín kí ẹ tó fi ìpìlẹ̀ tẹmpili yìí lélẹ̀. +Ninu oko tí ẹ tí ń retí pé ẹ óo rí ogún òṣùnwọ̀n ọkà, mẹ́wàá péré ni ẹ rí; níbi tí ẹ tí ń retí pé ẹ óo rí aadọta ìgò ọtí, ogún péré ni ẹ rí níbẹ̀. +Mo kọlù yín, mo sì mú kí atẹ́gùn gbígbóná ati yìnyín wó ohun ọ̀gbìn yín lulẹ̀, sibẹsibẹ ẹ kò ronupiwada, kí ẹ pada sọ́dọ̀ mi. +Lónìí ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, ni ẹ fi ìpìlẹ̀ tẹmpili lélẹ̀; láti òní lọ, ẹ kíyèsí ohun tí yóo máa ṣẹlẹ̀. +Kò sí ọkà ninu abà mọ, igi àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ kò sì tíì so; bẹ́ẹ̀ ni igi pomegiranate, ati igi olifi. Ṣugbọn láti òní lọ, n óo bukun yín.” +“Tún lọ sọ́dọ̀ Serubabeli ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù, kí o bèèrè pé, +Ní ọjọ́ kan náà, tíí ṣe ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, OLUWA tún rán Hagai, pé kí ó +sọ fún Serubabeli, gomina ilẹ̀ Juda pé òun OLUWA ní, “N óo mi ọ̀run ati ayé jìgìjìgì. +N óo lé àwọn ìjọba kúrò ní ipò wọn; n óo sì ṣẹ́ àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè lápá. N óo ta kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n lókìtì. Ẹṣin ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n yóo ṣubú, wọn óo sì fi idà pa ara wọn. +Ní ọjọ́ náà, n óo fi ìwọ Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ṣe aṣojú ninu ìjọba mi nítorí pé mo ti yàn ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.” +‘Àwọn wo ni wọ́n ṣẹ́kù ninu yín tí wọ́n rí i bí ẹwà ògo ilé yìí ti pọ̀ tó tẹ́lẹ̀? Báwo ni ẹ ti rí i sí nisinsinyii? Ǹjẹ́ ó jẹ́ nǹkankan lójú yín? +Ṣugbọn, mú ọkàn le, ìwọ Serubabeli, má sì fòyà, ìwọ Joṣua, ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa; ẹ ṣe ara gírí kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ náà ẹ̀yin eniyan; nítorí mo wà pẹlu yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí. +Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí mo ṣe fun yín, nígbà tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, mo wà láàrin yín; nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù.’ +“Nítorí pé èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ ọ́ pé láìpẹ́, n óo tún mi ọ̀run ati ayé jìgìjìgì lẹ́ẹ̀kan sí i, ati òkun ati ilẹ̀. +N óo mi gbogbo orílẹ̀-èdè, wọn óo kó ìṣúra wọn wá, n óo sì ṣe ilé yìí lọ́ṣọ̀ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí. +Tèmi ni gbogbo fadaka ati wúrà tí ó wà láyé; èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Ògo tí ilé yìí yóo ní tó bá yá, yóo ju ti àtijọ́ lọ. N óo fún àwọn eniyan mi ní alaafia ati ibukun ninu rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.” +Ẹwà Tẹmpili Tuntun náà. +Ọlọrun Sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ Rẹ̀. +Ní ìgbà àtijọ́, oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni Ọlọrun fi ń bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀. +Ó tún sọ pé,“O ti wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, Oluwa,ìwọ ni o fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀.Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni àwọn ọ̀run. +Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ óo wà títí.Gbogbo wọn óo gbó bí aṣọ. +Gẹ́gẹ́ bí eniyan tií ká aṣọ ni ìwọ óo ká wọn.Gẹ́gẹ́ bí aṣọ, a óo pààrọ̀ wọn.Ṣugbọn ní tìrẹ, bákan náà ni o wà.Kò sí òpin sí iye ọdún rẹ.” +Èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé,“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,títí n óo fi ṣe àwọn ọ̀tá rẹ ní àpótí ìtìsẹ̀ rẹ?” +Ṣebí ẹ̀mí tí ó jẹ́ iranṣẹ ni gbogbo àwọn angẹli. A rán wọn láti ṣiṣẹ́ nítorí àwọn tí yóo jogún ìgbàlà. +Ní àkókò ìkẹyìn yìí, ó wá bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó fi ṣe àrólé ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá ayé. +Ọmọ yìí jẹ́ ẹni tí ògo Ọlọrun hàn lára rẹ̀, ó sì jẹ́ àwòrán bí Ọlọrun ti rí gan-an. Òun ni ó mú kí gbogbo nǹkan dúró nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ eniyan nù tán, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá Ògo ní ibi tí ó ga jùlọ. +Ó ní ipò tí ó ga ju ti àwọn angẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ní orúkọ tí ó ju tiwọn lọ. +Nítorí èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé,“Ìwọ ni ọmọ mi,lónìí ni mo bí ọ?”Tabi tí ó sọ fún pé,“Èmi yóo jẹ́ baba fún un,òun náà yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi?” +Ṣugbọn nígbà tí ó mú àkọ́bí rẹ̀ wọ inú ayé, ohun tí ó sọ ni pé,“Kí gbogbo àwọn angẹliỌlọrun foríbalẹ̀ fún un.” +Ohun tí ó sọ nípa àwọn angẹli ni pé,“Ẹni tí ó ṣe àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀fúùfù,tí ó ṣe àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.” +Ṣugbọn ohun tí ó sọ fún Ọmọ náà ni pé,“Ìfẹ́ rẹ wà títí laelae, Ọlọrun,ọ̀pá òtítọ́ ni ọ̀pá ìjọba rẹ. +O fẹ́ràn òdodo, o kórìíra ẹ̀ṣẹ̀.Nítorí èyí, Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, fi òróró yàn ọ́láti gbé ọ ga ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.” +Ọ̀rọ̀ Ìyànjú ati Ìkìlọ̀. +Nítorí Òfin Mose jẹ́ òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀, kì í ṣe àwòrán wọn gan-an. Òfin ṣe ìlànà nípa irú ẹbọ kan náà tí àwọn eniyan yóo máa rú lọdọọdun. Ṣugbọn òfin kò lè sọ àwọn tí ń wá siwaju Ọlọrun di pípé. +Nípa ìfẹ́ Ọlọrun náà ni a fi yà wá sọ́tọ̀ nítorí ẹbọ tí Jesu fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. +Àwọn alufaa a máa dúró lojoojumọ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, láti máa rú ẹbọ kan náà tí kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ nígbàkúùgbà. +Ṣugbọn òun ṣe ìrúbọ lẹ́ẹ̀kan fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tó fún gbogbo ìgbà, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. +Níbẹ̀ ni ó wà tí ó ń retí ìgbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo di àpótí-ìtìsẹ̀ rẹ̀. +Nítorí nípa ẹbọ kan ó sọ àwọn tí a yà sọ́tọ̀ di pípé títí lae. +Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà fún wa. Ó kọ́kọ́ sọ báyìí pé, +“Èyí ni majẹmu tí n óo bá wọn dánígbà tí ó bá yá, Èmi Oluwa ni mo sọ bẹ́ẹ̀,Èmi óo fi òfin mi sí ọkàn wọn,n óo kọ wọ́n sí àyà wọn.” +Ó tún ní, “N kò ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú wọn mọ́.” +Nígbà tí a bá ti dárí àwọn nǹkan wọnyi ji eniyan, kò tún sí ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. +Nítorí náà, ẹ̀yin ará, a ní ìgboyà láti wọ Ibi Mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ ìkélé nípa ẹ̀jẹ̀ Jesu, +Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ẹbọ yìí ti sọ àwọn tí ń rú wọn di pípé ni, wọn kì bá tí rú wọn mọ́, nítorí ẹ̀rí-ọkàn wọn kì bá tí dá wọn lẹ́bi mọ́ bí ó bá jẹ́ pé ẹbọ tí wọ́n rú lẹ́ẹ̀kan bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́. +nípa ọ̀nà titun ati ọ̀nà ààyè tí ó ti yà sọ́tọ̀ fún wa tíí ṣe ẹran-ara rẹ̀. +A tún ní alufaa àgbà tí ó wà lórí ìdílé Ọlọrun. +Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn ati igbagbọ tí ó kún, kí á fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wẹ ọkàn wa mọ́, kí ó wẹ ẹ̀rí-ọkàn burúkú wa nù, kí á fi omi mímọ́ wẹ ara wa. +Kí á di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mú ṣinṣin láì ṣiyèméjì nítorí ẹni tí ó tó ó gbẹ́kẹ̀lé ni ẹni tí ó ṣe ìlérí. +Ẹ jẹ́ kí á máa rò nípa bí a óo ti ṣe fún ara wa ní ìwúrí láti ní ìfẹ́ ati láti ṣe iṣẹ́ rere. +Ẹ má jẹ́ kí á máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn mìíràn, ṣugbọn kí á máa gba ara wa níyànjú, pataki jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti rí i pé ọjọ́ ńlá ọ̀hún súnmọ́ tòsí. +Nítorí bí a bá mọ̀ọ́nmọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn tí a ti ní ìmọ̀ òtítọ́, kò tún sí ẹbọ kan tí a lè rú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. +Ohun tí ó kù ni pé kí á máa retí ìdájọ́ pẹlu ìpayà ati iná ńlá tí yóo pa àwọn ọ̀tá Ọlọrun. +Bí ẹni meji tabi mẹta bá jẹ́rìí pé ẹnìkan ṣá Òfin Mose tì, pípa ni wọn yóo pa olúwarẹ̀ láì ṣàánú rẹ̀. +Irú ìyà ńlá wo ni ẹ rò pé Ọlọrun yóo fi jẹ ẹni tí ó kẹ́gàn Ọmọ rẹ̀, tí ó rò pé nǹkan lásán ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí a fi yà á sọ́tọ̀, tí ó sì ṣe àfojúdi sí Ẹ̀mí tí a fi gba oore-ọ̀fẹ́? +Ṣugbọn àwọn ẹbọ wọnyi ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí lọdọọdun, +Nítorí a mọ ẹni tí ó sọ pé, “Tèmi ni ẹ̀san, Èmi yóo sì gbẹ̀san.” Ati pé, “Oluwa ni yóo ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ̀.” +Ohun tí ó bani lẹ́rù gidigidi ni pé kí ọwọ́ Ọlọrun alààyè tẹ eniyan. +Ẹ ranti bí a ti ja ìjà líle, tí ẹ farada ìrora, látijọ́, nígbà tí ẹ kọ́kọ́ rí ìmọ́lẹ̀ igbagbọ. +Nígbà mìíràn wọ́n fi yín ṣẹ̀sín, wọ́n jẹ yín níyà, àwọn eniyan ń fi yín ṣe ìran wò. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ẹ dúró láì yẹsẹ̀ pẹlu àwọn tí wọ́n ti jẹ irú ìyà bẹ́ẹ̀. +Bẹ́ẹ̀ ni ẹ bá àwọn ẹlẹ́wọ̀n jìyà. Pẹlu ayọ̀ ni ẹ fi gbà kí wọ́n fi agbára kó àwọn dúkìá yín lọ, nítorí ẹ mọ̀ pé ẹ ní dúkìá tí ó tún dára ju èyí tí wọn kó lọ, tí yóo sì pẹ́ jù wọ́n lọ. +Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ìfọkàntán tí ẹ ní bọ́, nítorí ó ní èrè pupọ. +Ohun tí ẹ nílò ni ìfaradà, kí ẹ lè ṣe ìf��̣ Ọlọrun, kí ẹ baà lè gba ìlérí tí ó ṣe. +Nítorí náà, bí Ìwé Mímọ́ ti wí,“Nítorí láìpẹ́ jọjọ,ẹni tí ń bọ̀ yóo dé,kò ní pẹ́ rárá. +Ṣugbọn àwọn olódodo tí wọ́n jẹ́ tèmiyóo wà láàyè nípa igbagbọ.Ṣugbọn bí èyíkéyìí ninu wọn bá fà sẹ́yìninú mi kò ní dùn sí i.” +Ṣugbọn àwa kò sí ninu àwọn tí wọn ń fà sẹ́yìn sí ìparun. Ṣugbọn àwa ní igbagbọ, a sì ti rí ìgbàlà. +nítorí ẹ̀jẹ̀ mààlúù ati ti ewúrẹ́ kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ. +Nítorí náà, nígbà tí Kristi wọ inú ayé wá, ó sọ fún Ọlọrun pé,“Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ ni o fẹ́,ṣugbọn o ti ṣe ètò ara kan fún mi. +Kì í ṣe ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ni o ní inú dídùn sí. +Nígbà náà ni mo sọ pé,‘Èmi nìyí.Àkọsílẹ̀ wà ninu Ìwé Mímọ́ nípa mi pé,Ọlọrun, mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.’ ” +Ní àkọ́kọ́ ó ní, “Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ tabi ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni o fẹ́, kì í ṣe àwọn ni inú rẹ dùn sí.” Àwọn ẹbọ tí wọn ń rú nìyí gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti Òfin. +Lẹ́yìn náà ó wá sọ pé, “Èmi nìyí, mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.” Èyí ni pé ó mú ti àkọ́kọ́ kúrò kí ó lè fi ekeji lélẹ̀. +Igbagbọ. +Igbagbọ ni ìdánilójú ohun tí à ń retí, ẹ̀rí tí ó dájú nípa àwọn ohun tí a kò rí. +Nítorí ó ń retí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀, tí ó jẹ́ pé Ọlọrun ni ó ṣe ètò rẹ̀ tí ó sì kọ́ ọ. +Nípa igbagbọ, Abrahamu ní agbára láti bímọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sara yàgàn, ó sì ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí, Abrahamu gbà pé ẹni tí ó ṣèlérí tó gbẹ́kẹ̀lé. +Nítorí èyí, láti ọ̀dọ̀ ẹyọ ọkunrin kan, tí ó ti dàgbà títí, tí ó ti kú sára, ni ọpọlọpọ ọmọ ti jáde, wọ́n pọ̀ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi iyanrìn etí òkun. +Gbogbo àwọn wọnyi kú ninu igbagbọ. Wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ṣe ìlérí gbà, òkèèrè ni wọ́n ti rí i, wọ́n sì ń fi ayọ̀ retí rẹ̀. Wọ́n jẹ́wọ́ pé àlejò tí ń rékọjá lọ ni àwọn ní ayé. +Àwọn eniyan tí ó bá ń sọ̀rọ̀ báyìí fihàn pé wọ́n ń wá ìlú ti ara wọn. +Bí ó bá jẹ́ pé wọ́n tún ń ronú ti ibi tí wọ́n ti jáde wá, wọn ìbá ti wá ààyè láti pada sibẹ. +Ṣugbọn wọ́n ń dàníyàn fún ìlú tí ó dára ju èyí tí wọ́n ti jáde kúrò lọ, tíí ṣe ìlú ti ọ̀run. Nítorí náà Ọlọrun kò tijú pé kí á pe òun ní Ọlọrun wọn, nítorí ó ti ṣe ètò ìlú kan fún wọn. +Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi Isaaki rúbọ nígbà tí Ọlọrun dán an wò. Ó fi ààyò ọmọ rẹ̀ rúbọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun ti ṣe ìlérí fún un nípa rẹ̀, +tí Ọlọrun ti sọ fún un pé, “Láti inú Isaaki ni ìdílé rẹ yóo ti gbilẹ̀.” +Èrò rẹ̀ ni pé Ọlọrun lè tún jí eniyan dìde ninu òkú. Nítorí èyí, àfi bí ẹni pé ó tún gba ọmọ náà pada láti inú òkú. +Igbagbọ ni àwọn àgbà àtijọ́ ní, tí wọ́n fi ní ẹ̀rí rere. +Nípa igbagbọ ni Isaaki fi súre fún Jakọbu ati Esau tí ó sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn. +Nígbà tí Jakọbu ń kú lọ, nípa igbagbọ ni ó fi súre fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Josẹfu. Ó ń sin Ọlọrun bí ó ti tẹríba lórí ọ̀pá rẹ̀. +Nígbà tí ó tó àkókò tí Josẹfu yóo kú, nípa igbagbọ ni ó fi ranti pé àwọn ọmọ Israẹli yóo jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì sọ bí òun ti fẹ́ kí wọ́n ṣe egungun òun. +Nígbà tí wọ́n bí Mose, nípa igbagbọ ni àwọn òbí rẹ̀ fi gbé e pamọ́ fún oṣù mẹta nítorí wọ́n rí i pé ọmọ tí ó lẹ́wà ni, wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba. +Nígbà tí Mose dàgbà tán, nípa igbagbọ ni ó fi kọ̀, tí kò jẹ́ kí wọ́n pe òun ní ọmọ ọmọbinrin Farao. +Ó kúkú yàn láti jìyà pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun jù pé kí ó jẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ lọ. +Ó ka ẹ̀gàn nítorí Mesaya sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju gbogbo ìṣúra Ijipti lọ, nítorí ó ń wo èrè níwájú. +Nípa igbagbọ ni ó fi kúrò ní Ijipti, kò bẹ̀rù ibinu ọba, ó ṣe bí ẹni tí ó rí Ọlọrun tí a kò lè rí, kò sì yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tí ó ti yàn. +Nípa igbagbọ ni ó fi ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ètò láti fi ẹ̀jẹ̀ ra ara ìlẹ̀kùn, kí angẹli tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ àwọn ará Ijipti má baà fọwọ́ kan ọmọ àwọn eniyan Israẹli. +Nípa igbagbọ ni àwọn ọmọ Israẹli fi gba ààrin òkun pupa kọjá bí ìgbà tí eniyan ń rìn lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nígbà tí àwọn ará Ijipti náà gbìyànjú láti kọjá, rírì ni wọ́n rì sinu omi. +Nípa igbagbọ ni ó fi yé wa pé ọ̀rọ̀ ni Ọlọrun fi dá ayé, tí ó fi jẹ́ pé ohun tí a kò rí ni ó fi ṣẹ̀dá ohun tí a rí. +Nípa igbagbọ ni odi ìlú Jẹriko fi wó lulẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti yí i ká fún ọjọ́ meje. +Nípa igbagbọ ni Rahabu aṣẹ́wó kò fi kú pẹlu àwọn alaigbagbọ, nígbà tí ó ti fi ọ̀yàyà gba àwọn amí. +Kí ni kí n tún wí? Àyè kò sí fún mi láti sọ nípa Gideoni, Baraki, Samsoni, Jẹfuta, Dafidi, Samuẹli ati àwọn wolii. +Nípa igbagbọ, wọ́n ṣẹgun ilẹ̀ àwọn ọba, wọn ṣiṣẹ́ tí òdodo fi gbilẹ̀, wọ́n rí ìlérí Ọlọrun gbà. Wọ́n pa kinniun lẹ́nu mọ́. +Wọ́n pa iná ńlá. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà. A sọ wọ́n di alágbára nígbà tí wọn kò ní ìlera. Wọ́n di akọni lójú ogun. Wọ́n tú àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ àjèjì ká tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá pada sẹ́yìn. +Àwọn obinrin gba àwọn eniyan wọn tí wọ́n ti kú pada lẹ́yìn tí a ti jí wọn dìde kúrò ninu òkú. A dá àwọn mìíràn lóró títí wọ́n fi kú. Wọn kò pé kí á dá wọn sílẹ̀, nítorí kí wọ́n lè gba ajinde tí ó dára jùlọ. +A fi àwọn mìíràn ṣẹ̀sín. Wọ́n fi kòbókò na àwọn mìíràn. A fi ẹ̀wọ̀n de àwọn mìíràn. A sọ àwọn mìíràn sẹ́wọ̀n. +A sọ àwọn mìíràn lókùúta. A fi ayùn rẹ́ àwọn mìíràn sí meji. A fi idà pa àwọn mìíràn. Àwọn mìíràn ń rìn kiri, wọ́n wọ awọ aguntan ati awọ ewúrẹ́, ninu ìṣẹ́ ati ìpọ́njú ati ìnira. +Wọ́n dára ju kí wọ́n wà ninu ayé lọ. Wọ́n ń dá rìn kiri ninu aṣálẹ̀, níbi tí eniyan kì í gbé, lórí òkè, ninu ihò inú òkúta ati ihò inú ilẹ̀. +Gbogbo àwọn wọnyi ni ẹ̀rí rere nípa igbagbọ, ṣugbọn wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ti ṣe ìlérí gbà. +Nípa igbagbọ ni Abeli fi rú ẹbọ tí ó dára ju ti Kaini lọ sí Ọlọrun. Igbagbọ rẹ̀ ni ẹ̀rí pé a dá a láre, nígbà tí Ọlọrun gba ọrẹ rẹ̀. Nípa igbagbọ ni ó fi jẹ́ pé bí ó tilẹ̀ ti kú, sibẹ ó ń sọ̀rọ̀. +Nítorí pé àwa ni Ọlọrun ní lọ́kàn tí ó fi ṣe ètò tí ó dára jùlọ, pé kí àwa ati àwọn lè jọ rí ẹ̀kún ibukun gbà. +Nípa igbagbọ ni a fi mú Enọku kúrò ní ayé láìjẹ́ pé ó kú. Ẹnikẹ́ni kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun ti mú un lọ. Nítorí kí ó tó mú un lọ, Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ pé, “Ó ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun.” +Láìsí igbagbọ eniyan kò lè ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun. Nítorí ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ Ọlọrun níláti gbàgbọ́ pé Ọlọrun wà, ati pé òun ni ó ń fún àwọn tí ó bá ń wá a ní èrè. +Nípa igbagbọ ni Noa fi kan ọkọ̀ kan, nígbà tí Ọlọrun ti fi àṣírí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ hàn án. Ó fi ọ̀wọ̀ gba iṣẹ́ tí Ọlọrun rán sí i, ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ìdílé rẹ̀. Nípa igbagbọ ó fi ìṣìnà aráyé hàn, ó sì ti ipa rẹ̀ di ajogún òdodo. +Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi gbà nígbà tí Ọlọrun pè é pé kí ó jáde lọ sí ilẹ̀ tí òun óo fún un. Ó jáde lọ láìmọ̀ ibi tí ó ń lọ. +Nípa igbagbọ ni ó fi ń gbé ilẹ̀ ìlérí bí àlejò, ó ń gbé inú àgọ́ bíi Isaaki ati Jakọbu, àwọn tí wọn óo jọ jogún ìlérí kan náà. +Ìtọ́ni ti Oluwa. +Níwọ̀n ìgbà tí a ní àwọn tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára igbagbọ, tí wọ́n yí wa ká bí awọsanma báyìí, ẹ jẹ́ kí á pa gbogbo ohun ìdíwọ́ tì sápá kan, ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti jẹ́ kí wọ́n dì mọ́ wa. Kí á fi ìfaradà sá iré ìje tí ó wà níwájú wa. +Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn baba wa nípa ti ara fi ń tọ́ wa, bí ó bá ti dára lójú wọn. Ṣugbọn Baba wa nípa ti ẹ̀mí ń tọ́ wa fún ire wa, kí á lè bá a pín ninu ìwà mímọ́ rẹ̀. +Ní àkókò tí a bá ń sọ fún eniyan pé: má ṣe èyí, má ṣe tọ̀hún, kì í dùn mọ́ ẹni tí à ń tọ́. Pẹlu ìnira ni. Ṣugbọn ní ìgbẹ̀yìn a máa so èso alaafia ti ìgbé-ayé òdodo fún àwọn tí a bá ti tọ́ sọ́nà. +Nítorí náà ẹ gbé ọwọ́ yín tí kò lágbára sókè, ẹ mú kí eékún yín tí ń gbọ̀n di alágbára; +ẹ ṣe ọ̀nà títọ́ fún ara yín láti máa rìn, kí ẹsẹ̀ tí ó bá ti rọ má baà yẹ̀, ṣugbọn kí ó lè mókun. +Ẹ máa lépa alaafia lọ́dọ̀ gbogbo eniyan pẹlu ìwà mímọ́. Láìṣe bẹ́ẹ̀ kò sí ẹni tí yóo rí Oluwa. +Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni ninu yín má fà sẹ́yìn kúrò ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe dàbí igi kíkorò, tí yóo dàgbà tán tí yóo wá fi ìkorò tirẹ̀ kó ìdààmú bá ọpọlọpọ ninu yín. +Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má jẹ́ oníṣekúṣe tabi alaigbagbọ bíi Esau, tí ó tìtorí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré ta anfaani tí ó ní gẹ́gẹ́ bí àrólé baba rẹ̀. +Ẹ mọ̀ pé nígbẹ̀yìn, nígbà tí ó fẹ́ gba ìre tí ó tọ́ sí àról��, baba rẹ̀ ta á nù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wá ọ̀nà àtúnṣe, kò sí ààyè mọ́ fún ìrònúpìwàdà. +Nítorí kì í ṣe òkè Sinai ni ẹ wá, níbi tí iná ti ń jó, tí ó ṣú dẹ̀dẹ̀ tí ó ṣókùnkùn tí afẹ́fẹ́ líle sì ń fẹ́, +tí fèrè ń dún kíkankíkan, tí ohùn kan wá ń sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ó jẹ́ pé àwọn tí ń gbọ́ ọ bẹ̀bẹ̀, pé kí àwọn má tún gbọ́ irú rẹ̀ mọ́. +Kí á máa wo Jesu olùpilẹ̀ṣẹ̀ ati aláṣepé igbagbọ wa. Ẹni tí ó farada agbelebu, kò sì ka ìtìjú ikú lórí agbelebu sí nǹkankan nítorí ayọ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. Ó ti wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun. +Nítorí ìjayà bá wọn nígbà tí a pàṣẹ fún wọn pé, “Bí ẹranko bá fi ara kan òkè náà, a níláti sọ ọ́ ní òkúta pa ni!” +Ohun tí wọ́n rí bani lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí Mose fi sọ pé, “Ẹ̀rù ń bà mí! Gbígbọ̀n ni gbogbo ara mi ń gbọ̀n látòkè délẹ̀.” +Ṣugbọn òkè Sioni ni ẹ wá, ìlú Ọlọrun alààyè, Jerusalẹmu ti ọ̀run, pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹrun angẹli. Ẹ wá sí àjọyọ̀ ogunlọ́gọ̀ eniyan, +ati ìjọ àwọn àkọ́bí tí a kọ orúkọ wọn sọ́run. Ẹ wá sọ́dọ̀ Ọlọrun onídàájọ́ gbogbo eniyan ati ọ̀dọ̀ ẹ̀mí àwọn ẹni rere tí a ti sọ di pípé, +ati ọ̀dọ̀ Jesu, alárinà majẹmu titun, ati sí ibi ẹ̀jẹ̀ tí a fi wọ́n ohun èèlò ìrúbọ tí ó ní ìlérí tí ó dára ju ti Abeli lọ. +Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣàì bìkítà fún ẹni tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé nígbà tí àwọn tí wọ́n ṣàì bìkítà fún Ọlọrun nígbà tí ó rán Mose ní iṣẹ́ sí ayé kò bọ́ lọ́wọ́ ìyà, báwo ni àwa ṣe le bọ́ bí a bá ṣàì bìkítà fún ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. +Ní àkókò náà ohùn rẹ̀ mi ilẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti ṣèlérí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i kì í ṣe ilẹ̀ nìkan ni n óo mì, ṣugbọn n óo mi ilẹ̀, n óo sì mi ọ̀run.” +Nígbà tí ó sọ pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ó dájú pé nígbà tí ó mi àwọn nǹkan tí a dá wọnyi, ó ṣetán láti mú wọn kúrò patapata, kí ó lè ku àwọn ohun tí a kò mì. +Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti gba ìjọba tí kò ṣe é mì, ẹ jẹ́ kí á dúpẹ́. Ẹ jẹ́ kí á sin Ọlọrun bí ó ti yẹ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ẹ̀rù; +nítorí iná ajónirun ni Ọlọrun wa. +Ẹ ro ti irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fọkàn rán àtakò àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ọkàn yín má baà rẹ̀wẹ̀sì. +Ninu ìjàkadì yín ẹ kò ì tíì tako ẹ̀ṣẹ̀ dé ojú ikú. +Ẹ ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Ìwé Mímọ́ níbi tí ó ti pè yín ní ọmọ, nígbà tí ó sọ pé,Ọmọ mi, má ṣe ka ìtọ́sọ́nà Oluwa sí nǹkan yẹpẹrẹmá sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá ń bá ọ wí. +Nítorí ẹni tí Oluwa bá fẹ́ràn ni ó ń tọ́ sọ́nà,ẹni tí ó bá gbà bí ọmọ,ni ó ń nà ní pàṣán. +Ẹ níláti faradà á bí ìtọ́sọ́nà. Ọlọrun mú yín bí ọmọ ni. Nítorí ọmọ wo ni ó wà tí baba rẹ̀ kò ní tọ́ sọ́nà? +Bí ẹ kò bá ní irú ìtọ́sọ́nà tí gbogbo ọmọ máa ń ní, á jẹ́ pé ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í ṣe ọmọ tòótọ́. +Ṣebí a ní àwọn baba tí wọ́n bí wa, tí wọn ń tọ́ wa sọ́nà, tí a sì ń bu ọlá fún wọn. Báwo ni ó wá yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún Baba wa nípa ti ẹ̀mí tó, kí á sì ní ìyè? +Ìsìn Tí Ó Wu Ọlọrun. +Àwọn onigbagbọ níláti fẹ́ràn ara wọn. +A ní pẹpẹ ìrúbọ kan tí àwọn alufaa tí wọn ń sìn ninu àgọ́ ti ayé kò ní àṣẹ láti jẹ ninu ẹbọ rẹ̀. +Nítorí nígbà tí Olórí Alufaa bá wọ Ibi Mímọ́ lọ, wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹranko rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn sísun ni wọ́n ń sun ẹran ẹbọ wọnyi lẹ́yìn ibùdó. +Bákan náà ni Jesu, ó jìyà lẹ́yìn odi ìlú kí ó lè sọ àwọn eniyan di mímọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkararẹ̀. +Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí á gba irú ẹ̀gàn tí ó gbà. +Nítorí a kò ní ìlú tí yóo wà títí níhìn-ín, ṣugbọn à ń retí èyí tí ó ń bọ̀! +Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa rú ẹbọ ìsìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo nípasẹ̀ Jesu. Èyí ni ohun tí ó yẹ gbogbo ẹni tí ó bá ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. +Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa fún àwọn ẹlòmíràn ninu àwọn ohun ìní yín. Irú ẹbọ yìí ni inú Ọlọrun dùn sí. +Kí ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn aṣiwaju yín lẹ́nu, kí ẹ máa tẹ̀lé ìlànà wọn. Nítorí wọ́n ń ṣe akitiyan láìṣe àárẹ̀ láti tọ́jú yín, pẹlu ọkàn pé wọn yóo jíyìn iṣẹ́ wọn fún Ọlọrun. Ẹ mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ayọ̀ fún wọn, ẹ má jẹ́ kí ó jẹ́ ��rora. Bí ẹ bá mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ìrora fún wọn, kò ní ṣe yín ní anfaani. +Ẹ máa gbadura fún wa. Ó dá wa lójú pé ọkàn wa mọ́. Ohun tí ó dára ni a fẹ́ máa ṣe nígbà gbogbo. +Nítorí náà mo tún bẹ̀ yín gidigidi pé kí ẹ máa gbadura fún wa, kí wọ́n baà lè dá mi sílẹ̀ kíákíá láti wá sọ́dọ̀ yín. +Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe àlejò nítorí nípa àlejò ṣíṣe àwọn ẹlòmíràn ti ṣe àwọn angẹli lálejò láìmọ̀ pé angẹli ni wọ́n. +Kí Ọlọrun alaafia, ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde ninu òkú, Jesu, Olú olùṣọ́-aguntan, ẹni tí ó kú, kí ó baà lè fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe èdìdì majẹmu ayérayé, kí ó mu yín pé ninu gbogbo ohun rere kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó lè máa ṣe ohun tí ó wù ú ninu yín nípasẹ̀ Jesu Kristi ẹni tí ògo wà fún lae ati laelae. Amin. +Mo bẹ̀ yín, ará, kí ẹ gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa yìí nítorí ìwé kúkúrú ni mo kọ si yín. +Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé wọ́n ti dá Timoti, arakunrin wa, sílẹ̀: ó ti jáde lẹ́wọ̀n. Bí ó bá tètè dé, èmi ati òun ni a óo jọ ri yín. +Ẹ kí gbogbo àwọn aṣiwaju yín ati gbogbo àwọn onigbagbọ. Àwọn ará láti Itali ki yín. +Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wà pẹlu gbogbo yín. +Ẹ ranti àwọn tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n, kí ẹ ṣe bí ẹni pé ẹ̀yin náà wà lẹ́wọ̀n pẹlu wọn. Ẹ tún ranti àwọn tí à ń ni lára pẹlu, nítorí pé inú ayé ni ẹ wà sibẹ, irú nǹkan wọnyi lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀yin náà. +Ohun tí ó lọ́lá ni igbeyawo. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì yẹ kí gbogbo yín kà á sí. Ibùsùn tọkọtaya gbọdọ̀ jẹ́ aláìléèérí. Nítorí Ọlọrun yóo dájọ́ fún àwọn oníṣekúṣe ati àwọn àgbèrè. +Ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà yín lọ́kàn. Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu ohun tí ẹ ní. Nítorí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti sọ pé, “N kò ní fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́!” +Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè fi ìgboyà sọ pé,“Oluwa ni olùrànlọ́wọ́ mi,ẹ̀rù kò ní bà mí.Ohun yòówù tí eniyan lè ṣe sí mi.” +Ẹ ranti àwọn aṣiwaju yín, àwọn tí wọ́n mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá fun yín. Ẹ ronú nípa iṣẹ́ wọn ati bí wọ́n ṣe kú. Kí ẹ ṣe àfarawé igbagbọ wọn. +Bákan náà ni Jesu Kristi wà lánàá, lónìí ati títí lae. +Ẹ má ṣe jẹ́ kí oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àjèjì mu yín ṣìnà. Ohun tí ó dára ni pé kí ọkàn yín gba agbára nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun, kì í ṣe nípa ìlànà ohun tí a jẹ, tabi ohun tí a kò jẹ, irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kò ṣe àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ní anfaani. +Ìgbàlà Ńlá. +Nítorí náà, ó yẹ kí á túbọ̀ ṣe akiyesi àwọn ohun tí à ń gbọ́, kí á má baà gbá wa lọ bí ìgbà tí odò gbá nǹkan lọ. +Nítorí pé kí Ọlọrun tí ó dá gbogbo nǹkan, tí ó sì mú kí gbogbo nǹkan wà, lè mú ọpọlọpọ wá sí inú ògo, ó tọ́ kí ó ṣe aṣaaju tí yóo la ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún wọn nípa ìyà jíjẹ. +Nítorí ọ̀kan ni ẹni tí ó ń ya eniyan sí mímọ́ ati àwọn eniyan tí ó ń yà sí mímọ́ jẹ́, nítorí náà ni Jesu kò fi tijú láti pè wọ́n ní arakunrin rẹ̀. +Ó ní,“Èmi óo pe orúkọ rẹ ní gbangba fún àwọn arakunrin mi.Ní ààrin àwùjọ ni n óo yìn ọ́.” +Ó tún sọ pé,“Èmi ní tèmi, èmi óo gbẹ́kẹ̀lé e.”Ati pé,“Èmi nìyí ati àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi fún mi.” +Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ jẹ́ ẹlẹ́ran-ara ati ẹlẹ́jẹ̀, Jesu pàápàá di ẹlẹ́ran-ara ati ẹlẹ́jẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wọn, kí ó lè ti ipasẹ̀ ikú rẹ̀ sọ agbára Satani tí ó ní ikú ní ìkáwọ́ di asán. +Ó wá dá àwọn tí ẹ̀rù ikú ti sọ di ẹrú ninu gbogbo ìgbé-ayé wọn sílẹ̀. +Nítorí ó dájú pé, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó wá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún bíkòṣe àwọn ọmọ Abrahamu. +Nítorí náà, dandan ni kí òun alára jọ àwọn arakunrin rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, kí ó lè jẹ́ Olórí Alufaa tí ó láàánú, tí ó sì ṣe é gbójú lé nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ níwájú Ọlọrun fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan. +Nítorí níwọ̀n ìgbà tí òun alára ti jìyà, ó lè ran àwọn tí wọ́n wà ninu ìdánwò lọ́wọ́. +Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu àwọn angẹli sọ bá fẹsẹ̀ múlẹ̀, tí gbogbo ìwà àìṣedéédé ati ìwà àìgbọràn bá gba ìbáwí tí ó tọ́ sí wọn, +báwo ni a óo ti ṣe sá àsálà, tí a bá kọ etí-ikún sí ìgbàlà tí ó tóbi tó báyìí? Oluwa fúnrarẹ̀ ni ó kọ́kọ́ kéde ìgbàlà yìí ní ìbẹ̀rẹ̀. Àwọn tí wọ́n gbọ́ ni wọ́n fún wa ní ìdánilójú pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí. +Ọlọrun pàápàá tún jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà nípa àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó ju agbára ẹ̀dá lọ, tí ó ṣe nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀. +Nítorí kì í ṣe àwọn angẹli ni ó fún ní àṣẹ láti ṣe àkóso ayé tí ń bọ̀, èyí tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀. +Ó wà ní àkọsílẹ̀ níbi tí ẹnìkan ti sọ pé,“Kí ni eniyan, tí o fi ń ranti rẹ̀,tabi ọmọ eniyan tí o fi ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀? +O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ ju ti àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀.O sì fi ògo ati ọlá dé e ládé. +O fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.”Nítorí pé ó fi gbogbo nǹkan wọnyi sí ìkáwọ́ rẹ̀, kò ku nǹkankan tí kò sí ní ìkáwọ́ rẹ̀. Ṣugbọn nígbà náà, a kò ì tíì rí i, pé gbogbo nǹkan ni ó ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. +Ṣugbọn a rí Jesu, tí Ọlọrun fi sí ipò tí ó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju ti àwọn angẹli fún àkókò díẹ̀. Òun ni ó jẹ oró ikú, tí Ọlọrun tún wá fi ògo ati ọlá dé e ládé. Nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ó kú fún gbogbo eniyan. +Jesu Ju Mose Lọ. +Nítorí náà, ẹ̀yin ará ninu Oluwa, tí a jọ ní ìpín ninu ìpè tí ó ti ọ̀run wá, ẹ ṣe akiyesi Jesu, tíí ṣe òjíṣẹ́ ati Olórí Alufaa ìjẹ́wọ́ igbagbọ wa. +Nítorí náà, mo bínú sí ìran wọn.Mo ní, ‘Nígbà gbogbo ni wọ́n máa ń ṣìnà ní ọkàn wọn.Iṣẹ́ mi kò yé wọn.’ +Ni mo bá búra pẹlu ibinu,pé wọn kò ní dé ibi ìsinmi mi.” +Ẹ kíyèsára, ará, kí ó má ṣe sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí yóo ní inú burúkú tóbẹ́ẹ̀ ti kò ní ní igbagbọ, tí yóo wá pada kúrò lẹ́yìn Ọlọrun alààyè. +Ṣugbọn ẹ máa gba ara yín níyànjú lojoojumọ níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ “Òní” tí Ìwé Mímọ́ sọ bá ti bá àwa náà wí, kí ẹ̀ṣẹ̀ má baà tan ẹnikẹ́ni lọ, kí ó sì mú kí ó ṣe agídí sí Ọlọrun. +Nítorí a ti di àwọn tí ó ń bá Kristi kẹ́gbẹ́ bí a bá fi ọkàn tán an títí dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti fi ọkàn tán an ní ìbẹ̀rẹ̀ igbagbọ wa. +Bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,ẹ má ṣe agídí gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ọ̀tẹ̀.” +Mò ń bèèrè, àwọn ta ni ó gbọ́ tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀? Ṣebí gbogbo àwọn tí wọ́n bá Mose jáde kúrò ní Ijipti ni. +Àwọn ta ni Ọlọrun bínú sí ní ogoji ọdún? Ṣebí àwọn tí ó ṣẹ̀ ni, tí òkú wọn wà káàkiri ní aṣálẹ̀. +Àwọn ta ni ó búra pé wọn kò ní wọ inú ìsinmi òun? Ṣebí àwọn aláìgbọràn ni. +A rí i pé wọn kò lè wọ inú ìsinmi yìí nítorí wọn kò gbàgbọ́. +Ẹ rí i pé ó ṣe olóòótọ́ sí Ọlọrun tí ó yàn án gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣe oloòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun. +Nítorí bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti ní ọlá ju ilé tí ó kọ́ lọ, bẹ́ẹ̀ ni Jesu yìí ní ọlá ju Mose lọ. +Nítorí kò sí ilé kan tí kò jẹ́ pé eniyan ni ó kọ́ ọ. Ṣugbọn Ọlọrun ni ó ṣe ohun gbogbo. +Mose ṣe olóòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ. A rán an láti jẹ́rìí sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun yóo fi fún un láti sọ ni. +Ṣugbọn Kristi ṣe olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ninu ìdílé rẹ̀. Àwa gan-an ni ìdílé rẹ̀ náà, bí a bá dúró pẹlu ìgboyà tí à ń ṣògo lórí ìrètí wa. +Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí,“Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀, +ẹ má ṣe agídí, gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ìṣọ̀tẹ̀,ní àkókò ìdánwò ninu aṣálẹ̀, +nígbà tí àwọn baba-ńlá yín dán mi wò,tí wọ́n fi rí iṣẹ́ mi fún ogoji ọdún. +Jesu Olórí Alufaa Ńlá. +Nítorí náà níwọ̀n ìgbà tì ìlérí àtiwọ inú ìsinmi rẹ̀ tún wà, ẹ jẹ́ kí á ṣọ́ra gidigidi kí ẹnikẹ́ni ninu yín má baà kùnà láti wọ̀ ọ́. +Nítorí ẹni tí ó bá wọ inú ìsinmi rẹ̀ ti sinmi ninu iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sinmi ninu tirẹ̀. +Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á sa gbogbo ipá wa láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú ati àìgbọràn bíi ti àwọn tí à ń sọ̀rọ̀ wọn. +Nítorí pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè, ó sì lágbára. Ó mú ju idà olójú meji lọ. Ó mú tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi lè gé ẹ̀mí kúrò lára ọkàn, ó sì lè rẹ́ mùdùnmúdùn kúrò lára àwọn oríkèé ara. Ó yára láti mọ ète ati èrò ọkàn eniyan. +Kò sí ẹ̀dá kan tí ó lè fara pamọ́ níwájú rẹ̀. Gbogbo nǹkan ṣípayá kedere níwájú Ọlọrun, ẹni tí a óo jíyìn iṣẹ́ wa fún. +Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ní Olórí Alufaa ńlá tí ó ti kọjá lọ sí ọ̀run tíí ṣe Jesu Ọmọ Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí á di ohun ti a fi igbagbọ jẹ́wọ́ mú ṣinṣin. +Nítorí Olórí Alufaa tí a ní kì í ṣe ẹni tí kò lè bá wa kẹ́dùn ninu àwọn àìlera wa. Ṣugbọn ó jẹ́ ��ni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bíi wa, ṣugbọn òun kò dẹ́ṣẹ̀. +Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á fi ìgboyà súnmọ́ ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́, kí á lè rí àánú gbà, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, kí á lè rí ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀. +Nítorí àwa náà ti gbọ́ ìyìn rere bí àwọn tọ̀hún ti gbọ́. Ṣugbọn ọ̀rọ̀ tí àwọn gbọ́ kò ṣe wọ́n ní anfaani, nítorí wọn kò ní igbagbọ ninu ohun tí wọ́n gbọ́. +Àwa tí a gbàgbọ́ ni a wọ inú ìsinmi náà. Nígbà tí Ọlọrun sọ pé,“Mo búra pẹlu ibinu pé,wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.”Ó sọ bẹ́ẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti parí iṣẹ́ rẹ̀ láti ìpìlẹ̀ ayé. +Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ níbìkan nípa ọjọ́ keje pé, “Ọlọrun sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ keje.” +Lẹ́ẹ̀kan sí i, ohun tí ó sọ ní ibí yìí ni pé, “Wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.” +Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ará àtijọ́ tí wọ́n gbọ́ ìyìn rere kò wọ inú ìsinmi náà nítorí àìgbọràn, nítorí náà ó ku àwọn kan tí wọn yóo wọ inú rẹ̀. +Ọlọrun wá tún yan ọjọ́ mìíràn. Ninu ìwé Dafidi, tí ó kọ lẹ́yìn ọdún pupọ, ó sọ pé, “Lónìí”, níbi tí atọ́ka sí, tí ó kà báyìí pé,“Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,Ẹ má ṣe agídí.” +Bí ó bá jẹ́ pé Joṣua fún wọn ní ìsinmi ni, Ọlọrun kò ní tún sọ nípa ọjọ́ mìíràn mọ́ lẹ́yìn ọjọ́ pupọ. +Nítorí náà, ìsinmi ọjọ́ ìsinmi wà nílẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun. +Ìkìlọ̀ nípa Àwọn tí Ó Kúrò ninu Ẹ̀sìn Igbagbọ. +Nítorí ẹnikẹ́ni tí a bá yàn láàrin àwọn eniyan láti jẹ́ olórí alufaa, a yàn án bí aṣojú àwọn eniyan níwájú Ọlọrun, kí ó lè máa mú àwọn ọrẹ ati ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn wá siwaju Ọlọrun. +Òun ni Ọlọrun pè ní olórí alufaa gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki. +A ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ fun yín nípa Mẹlikisẹdẹki yìí. Ọ̀rọ̀ náà ṣòro láti túmọ̀ nígbà tí ọkàn yín ti le báyìí. +Nítorí ó ti yẹ kí ẹ di olùkọ́ni ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́. Sibẹ ẹ tún wà ninu àwọn tí a óo máa kọ́ ní “A, B, D,” nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti Ọlọrun. Ẹ wà ninu àwọn tí a óo máa fi wàrà bọ́, ẹ kò ì tíì lè jẹ oúnjẹ gidi. +Nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá sì ń mu wàrà, kò tíì mọ ẹ̀kọ́ nípa òdodo, nítorí ọmọ-ọwọ́ ni irú wọn. +Ṣugbọn oúnjẹ gidi ni àgbàlagbà máa ń jẹ, àwọn tí ìrírí wọn fún ọjọ́ pípẹ́ ti fún ní òye láti mọ ìyàtọ̀ láàrin nǹkan rere ati nǹkan burúkú. +Ó lè fi sùúrù bá àwọn tí wọ́n ṣìnà nítorí wọn kò gbọ́ lò, nítorí pé eniyan aláìlera ni òun náà. +Nítorí èyí, bí ó ti ń rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti òun alára. +Kò sí ẹni tíí yan ara rẹ̀ sí ipò yìí. Ṣugbọn àwọn tí Ọlọrun bá pè ni à ń yàn, bíi Aaroni. +Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, Kristi náà kò yan ògo yìí fúnrarẹ̀, láti jẹ́ olórí alufaa. Ọlọrun ni ó yàn án. Ọlọrun ni ó sọ fún un pé,“Ìwọ ni Ọmọ mi,lónìí ni mo bí ọ.” +Bẹ́ẹ̀ náà ni ó sọ ní ibòmíràn pé,“Alufaa ni ọ́ títí laelaegẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.” +Ní ìgbà ayé Jesu, pẹlu igbe ńlá ati ẹkún, ó fi adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ siwaju ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ ikú. Nítorí pé ó bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, adura rẹ̀ gbà. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ ni, ó kọ́ láti gbọ́ràn nípa ìyà tí ó jẹ. +Nígbà tí a ti ṣe é ní àṣepé, ó wá di orísun ìgbàlà tí kò lópin fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbà á gbọ́. +Ìlérí Ọlọrun Tí Ó Dájú. +Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa ẹ̀kọ́ alakọọbẹrẹ ti ìsìn igbagbọ tì, kí á tẹ̀síwájú láti kọ́ ẹ̀kọ́ tí ó jinlẹ̀. Kí á má tún máa fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ mọ́, ìpìlẹ̀ bí ẹ̀kọ́ nípa ìrònúpìwàdà kúrò ninu àwọn iṣẹ́ tí ó yọrí sí ikú, ẹ̀kọ́ nípa igbagbọ ninu Ọlọrun; +Nítorí Ọlọrun kì í ṣe alaiṣootọ, tí yóo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ yín tí ẹ fihàn sí orúkọ rẹ̀, nígbà tí ẹ ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn onigbagbọ, bí ẹ ti tún ń ṣe nisinsinyii. +Ìfẹ́ ọkàn wa ni pé kí olukuluku yín fi ìtara kan náà hàn, tí ẹ fi lè ní ẹ̀kún ìrètí yín títí dé òpin; +kí ẹ má jẹ́ òpè, ṣugbọn kí ẹ fara wé àwọn tí wọ́n fi igbagbọ ati sùúrù jogún àwọn ìlérí Ọlọrun. +Nítorí nígbà tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún Abrahamu, ara rẹ̀ ni ó fi búra nígbà tí kò sí ẹnìkan tí ó tóbi bíi rẹ̀ tí ìbá fi búra. +Ó ní, “Ní ti ibukun, n óo bukun ọ. Ní ti kí eniyan pọ̀, n óo sọ ọ́ di pupọ.” +Bẹ́ẹ̀ ni Abrahamu ṣe gba ìlérí náà pẹlu sùúrù. +Ẹni tí ó bá juni lọ ni a fi í búra. Ọ̀rọ̀ tí eniyan bá sì ti búra lé lórí, kò sí àríyànjiyàn lórí rẹ̀ mọ́. +Ní ọ̀nà kan náà, nígbà tí Ọlọrun fẹ́ fihàn gbangba fún àwọn ajogún ìlérí wí pé èrò òun kò yipada, ó ṣe ìlérí, ó sì fi ìbúra tì í. +Èyí ni pé nípa ohun meji tí kò ṣe é yipada, tí Ọlọrun kò sì lè fi purọ́ ni àwa tí a sá di Ọlọrun fi lè ní ìwúrí pupọ láti di ìlérí tí ó wà níwájú wa mú. +A di ìlérí náà mú. Ó dàbí ìdákọ̀ró fún ọkàn wa. Ìlérí yìí dájú, ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Ó ti wọ inú yàrá tí ó wà ninu, lẹ́yìn aṣọ ìkélé, +ẹ̀kọ́ nípa ìrìbọmi, ìgbé-ọwọ́-lé eniyan lórí, ajinde kúrò ninu òkú, ati ìdájọ́ ìkẹyìn. +níbi tí Jesu aṣiwaju wa ti wọ̀ lọ, tí ó di olórí alufaa títí lae gẹ́gẹ́ bíi Mẹlikisẹdẹki. +Ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú nípa kíkọ́ ẹ̀kọ́ tí ó jinlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni a óo sì ṣe, bí Ọlọrun bá fẹ́. +Nítorí àwọn tí a bá ti là lójú, tí wọ́n ti tọ́wò ninu ẹ̀bùn tí ó ti ọ̀run wá, àwọn tí wọ́n ti ní ìpín ninu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, +tí wọ́n ti tọ́ ire tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ Ọlọrun wò, ati agbára ayé tí ó ń bọ̀, +tí wọ́n bá wá yipada kúrò ninu ìsìn igbagbọ, kò sí ohun tí a lè ṣe tí wọ́n fi lè tún ronupiwada mọ́, nítorí wọ́n ti tún fi ọwọ́ ara wọn kan Ọmọ Ọlọrun mọ́ agbelebu, wọ́n sọ ikú rẹ̀ di nǹkan àwàdà. +Nítorí nígbà tí ilẹ̀ bá ń mu omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó sì ń mú kí ohun ọ̀gbìn hù fún àwọn àgbẹ̀ tí ń roko níbẹ̀, ilẹ̀ náà ń gba ibukun Ọlọrun ni. +Ṣugbọn bí ó bá ń hu ẹ̀gún ati igikígi, kò wúlò, kò sì ní pẹ́ tí Ọlọrun yóo fi fi í gégùn-ún. Ní ìkẹyìn, iná ni a óo dá sun ún. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń sọ̀rọ̀ báyìí, sibẹ ó dá wa lójú nípa tiyín, ẹ̀yin àyànfẹ́, pé ipò yín dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ ní ohun tí ó yẹ fún ìgbàlà. +Irú Alufaa tí Mẹlikisẹdẹki Jẹ́. +Nítorí Mẹlikisẹdẹki yìí jẹ́ ọba Salẹmu ati alufaa Ọlọrun Ọ̀gá Ògo. Òun ni ó pàdé Abrahamu nígbà tí Abrahamu ń pada bọ̀ láti ojú-ogun lẹ́yìn tí ó bá ọba mẹrin jà, tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa. Ó bá súre fún Abrahamu. +nítorí a lè sọ pé ó wà ní ara Abrahamu baba-ńlá rẹ̀ nígbà tí Mẹlikisẹdẹki pàdé rẹ̀. +Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé ètò iṣẹ́ alufaa ti ìdílé Lefi kò ní àbùkù, tí ó sì jẹ́ pé nípa rẹ̀ ni àwọn eniyan fi gba òfin, kí ló dé tí a fi tún ṣe ètò alufaa ní ìgbésẹ̀ Mẹlikisẹdẹki, tí kò fi jẹ́ ti Aaroni? +Nítorí bí a bá yí ètò iṣẹ́ alufaa pada, ó níláti jẹ́ pé a yí òfin náà pada. +Ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí wá láti inú ẹ̀yà mìíràn. Ninu ẹ̀yà yìí ẹ̀wẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ní nǹkankan ṣe pẹlu ẹbọ rírú. +Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Oluwa wa ti wá. Mose kò sì sọ ohunkohun tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ alufaa nípa ẹ̀yà yìí. +Ohun tí à ń sọ hàn kedere nígbà tí a rí i pé a yan alufaa mìíràn gẹ́gẹ́ bí àwòrán Mẹlikisẹdẹki, +ẹni tí ó di alufaa nípa agbára ìyà tí kò lópin, tí kì í ṣe nípa ìlànà àṣẹ tí a ti ọwọ́ eniyan ṣe ètò. +Nítorí a rí ẹ̀rí níbìkan pé,“Ìwọ yóo jẹ́ alufaa títí lae,gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.” +A pa àṣẹ ti àkọ́kọ́ tì nítorí kò lágbára, kò sì wúlò. +Nítorí kò sí ohun tí òfin sọ di pípé. A wá ṣe ètò ìrètí tí ó dára ju òfin lọ nípa èyí tí a lè fi súnmọ́ Ọlọrun. +Abrahamu fún un ní ìdámẹ́wàá gbogbo ìkógun. Ní àkọ́kọ́, ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ ni “ọba òdodo.” Lẹ́yìn náà, ó tún jẹ́ ọba Salẹmu, èyí ni “ọba alaafia.” +Ìrètí yìí ní ìbúra ninu. Àwọn ọmọ Lefi di alufaa láìsí ìbúra. +Ṣugbọn pẹlu ìbúra ni, nígbà tí Ọlọrun sọ fún un pé,“Oluwa ti búra,kò ní yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada:‘Ìwọ máa jẹ́ alufaa títí lae.’ ” +Báyìí ni Jesu ṣe di onígbọ̀wọ́ majẹmu tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ. +Àwọn alufaa ìdílé Lefi pọ̀ nítorí ikú kò jẹ́ kí èyíkéyìí ninu wọn lè wà títí ayé. +Ṣugbọn ní ti Jesu, ó wà títí. Nítorí náà kò sí ìdí tí a óo fi tún yan alufaa mìíràn dípò rẹ̀. +Ìdí nìyí tí ó fi lè gba àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ rẹ̀ là, lọ́nà gbogbo títí lae nítorí pé ó wà láàyè títí láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn. +Irú olórí alufaa bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ wá. Ẹni mímọ́; tí kò ní ẹ̀tàn, tí kò ní àbùkù, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́, tí a gbé ga kọjá àwọn ọ̀run. +Òun kì í ṣe ẹni tí ó níláti kọ́kọ́ rúbọ lojoojumọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀, kí ó tó wá rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan, bí àwọn olórí alufaa ti ìdílé Lefi ti ń ṣe. Nítorí lẹ́ẹ̀kan náà ni ó ti ṣe èyí, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ. +Nítorí àwọn tí à ń yàn bí olórí alufaa lábẹ́ òfin Mose jẹ́ eniyan, wọ́n sì ní àìlera. Ṣugbọn olórí alufaa tí a yàn nípa ọ̀rọ̀ ìbúra tí ó dé lẹ́yìn òfin ni Ọmọ Ọlọrun tí a ṣe ní àṣepé títí lae. +Kò sí àkọsílẹ̀ pé ó ní baba tabi ìyá; kò ní ìtàn ìdílé. Kò sí àkọsílẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tabi òpin ìgbé-ayé rẹ̀. Ó jẹ́ àwòrán Ọmọ Ọlọrun. Ó jẹ́ alufaa nígbà gbogbo. +Ẹ kò rí bí ọkunrin yìí ti jẹ́ eniyan pataki tó, tí Abrahamu baba-ńlá wa fi fún un ní ìdámẹ́wàá àwọn nǹkan àṣàyàn ninu ìkógun rẹ̀. +Àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n ní àṣẹ láti gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn eniyan gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin. Wọ́n ń gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn eniyan wọn tí wọ́n jẹ́ ìran Abrahamu. +Ṣugbọn Mẹlikisẹdẹki tí kì í ṣe ìran Abrahamu gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì súre fún Abrahamu tí ó rí àwọn ìlérí Ọlọrun gbà. +Láìṣe àní-àní, ẹni tí ó bá tóbi ju eniyan lọ níí súre fún un. +Ati pé, àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gba ìdámẹ́wàá, ẹni tí yóo kú ni wọ́n. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ sọ nípa Mẹlikisẹdẹki pé ó wà láàyè. +A lè sọ pé nígbà tí Abrahamu san ìdámẹ́wàá, Lefi tí ń gba ìdámẹ́wàá náà san ìdámẹ́wàá, +Olórí Alufaa ti Majẹmu Titun. +Kókó ohun tí à ń sọ nìyí, pé a ní irú Olórí Alufaa báyìí, ẹni tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ ọlá ńlá ní ọ̀run. +Èyí ni majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tí ó bá yá. N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo kọ ọ́ sí ọkàn wọn, èmi óo jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi. +Kì yóo sí ìdí tí ẹnìkan yóo fi kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀, pé,‘Mọ Oluwa.’Nítorí pé gbogbo wọn ni wọn óo mọ̀ mí,ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí àwọn mẹ̀kúnnù inú wọn títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki. +Nítorí n óo fi àánú fojú fo ìwà burúkú wọn,n kò sì ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” +Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ nípa majẹmu titun, ohun tí ó ń sọ ni pé ti àtijọ́ ti di ògbólógbòó. Ohun tí ó bá sì ti di ògbólógbòó, kò níí pẹ́ parẹ́. +Òun yìí ni òjíṣẹ́ ní ilé ìsìn tí ó mọ́ jùlọ tíí ṣe àgọ́ tòótọ́, tí Oluwa fúnrarẹ̀ kọ́, kì í ṣe èyí tí eniyan kọ́. +Nítorí gbogbo Olórí Alufaa tí a bá yàn, a yàn wọ́n pé kí wọ́n máa mú ẹ̀bùn ati ẹbọ àwọn eniyan wá siwaju Ọlọrun ni. Bákan náà ni òun náà níláti ní àwọn ohun tí yóo máa mú wá siwaju Ọlọrun. +Bí ó bá jẹ́ pé ó wà ninu ayé, kì bá tí jẹ́ alufaa rárá, nítorí àwọn alufaa wà tí wọn ń mú ẹ̀bùn àwọn eniyan lọ siwaju Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin. +Àwọn yìí ń ṣe ìsìn wọn ninu ilé ìsìn tí ó jẹ́ ẹ̀dà ati àfijọ ti ọ̀run. A rí i pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí nítorí nígbà tí Mose fẹ́ kọ́ àgọ́, ohun tí Ọlọrun sọ fún un ni pé, “Ṣe akiyesi pé o ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí mo fihàn ọ́ ní orí òkè.” +Ṣugbọn nisinsinyii iṣẹ́ ìsìn ti Olórí Alufaa wa dára pupọ ju ti àwọn ọmọ Lefi lọ, nítorí pé majẹmu tí ó jẹ́ alárinà fún dára ju ti àtijọ́ lọ, ìdí ni pé ìlérí tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ ni majẹmu yìí dúró lé lórí. +Bí majẹmu ti àkọ́kọ́ kò bá ní àbùkù, kò sí ìdí tí à bá fi fi òmíràn dípò rẹ̀. +Nítorí Ọlọrun rí ẹ̀ṣẹ̀ kà sí wọn lọ́rùn ni ó fi sọ pé,“Oluwa wí pé:Ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi yóo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun. +Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba wọn dání ọjọ́ tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.Nítorí wọn kò pa majẹmu mi mọ́,mo bá kẹ̀yìn sí wọn. +Ilé Ìsìn Ti Ayé ati Ti Ọ̀run. +Majẹmu àkọ́kọ́ ni àwọn ètò ìsìn ati ilé ìsìn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ti ayé ni. +Ohun tí a rí dì mú ninu wọn kò ju nípa jíjẹ ati mímu lọ, ati nípa oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìwẹ ọwọ́, wẹ ẹsẹ̀. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìlànà àwọn nǹkan tí a lè fojú rí, tí yóo sì máa wà títí di àkókò àtúnṣe. +Ṣugbọn Kristi ti dé, òun sì ni Olórí Alufaa àwọn ohun rere tí ó wà. Ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ninu àgọ́ tí ó pé tí ó sì tóbi ju ti àtijọ́ lọ, àgọ́ tí a kò fi ọwọ́ kọ́, tí kì í sì í ṣe ti ẹ̀dá ayé yìí. +Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ tabi ti mààlúù bíkòṣe è��jẹ̀ ara rẹ̀, ni ó fi rúbọ, nígbà tí ó wọ inú Ibi Mímọ́ jùlọ lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ṣe ìràpadà ayérayé fún wa. +Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ ati ti mààlúù ati eérú abo mààlúù tí a bù wọ́n àwọn tí wọ́n bá ṣe ohun èérí nípa ẹ̀sìn bá sọ wọ́n di mímọ́ lóde ara, +mélòó-mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ tí kò lábùkù sí Ọlọrun nípa Ẹ̀mí ayérayé, yóo wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò ninu iṣẹ́ tíí yọrí sí ikú, tí yóo sì fi ṣe wá yẹ fún ìsìn Ọlọrun alààyè. +Nítorí èyí, òun ni alárinà majẹmu. Ó kú kí ó lè ṣe ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ tí eniyan dá lábẹ́ majẹmu àkọ́kọ́, kí àwọn tí Ọlọrun pè lè gba ìlérí ogún ayérayé. +Nítorí bí eniyan bá ṣe ìwé bí òun ti fẹ́ kí wọ́n pín ogún òun, ìdánilójú kọ́kọ́ gbọdọ̀ wà pé ó ti kú kí ẹnikẹ́ni tó lè mú ìwé náà lò. +Ìwé ìpíngún kò wúlò níwọ̀n ìgbà tí ẹni tí ó ṣe é bá wà láàyè. Ó di ìgbà tí ó bá kú. +Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé pẹlu ẹ̀jẹ̀ ni a fi ṣe majẹmu àkọ́kọ́. +Gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin, nígbà tí Mose bá ti ka gbogbo àṣẹ Ọlọrun fún àwọn eniyan tán, a mú ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ mààlúù ati ti ewúrẹ́ pẹlu omi, ati òwú pupa ati ẹ̀ka igi hisopu, a fi wọ́n Ìwé Òfin náà ati gbogbo àwọn eniyan. +Nítorí wọ́n pa àgọ́ àkọ́kàn, ninu rẹ̀ ni ọ̀pá fìtílà ati tabili wà. Lórí tabili yìí ni burẹdi máa ń wà, níwájú Oluwa nígbà gbogbo. Èyí ni à ń pè ní Ibi Mímọ́. +A wá sọ pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí Ọlọrun pa láṣẹ fun yín.” +Bákan náà ni yóo fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n ara àgọ́ náà ati gbogbo ohun èèlò ti ìsìn. +Gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti òfin, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan pátá ni à ń fi ẹ̀jẹ̀ sọ di mímọ́, ati pé láìsí ìtasílẹ̀ ẹ̀jẹ̀ kò lè sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. +Nítorí náà, nígbà tí ó jẹ́ pé a níláti fi ẹbọ sọ ẹ̀dà àwọn nǹkan ti ọ̀run di mímọ́, a rí i pé àwọn nǹkan ti ọ̀run fúnra wọn nílò ẹbọ tí ó dára ju èyí tí ẹ̀dà wọn gbà lọ. +Nítorí kì í ṣe àgọ́ tí a fi ọwọ́ kọ́ ni Kristi wọ̀ lọ, èyí tíí ṣe ẹ̀dà ti àgọ́ tòótọ́. Ṣugbọn ọ̀run gan-an ni ó wọ̀ lọ, nisinsinyii ó wà níwájú Ọlọrun nítorí tiwa. +Kì í sìí ṣe pé à-rú-tún-rú ni yóo máa fi ara rẹ̀ rúbọ, bí Olórí Alufaa ti ìdílé Lefi ti máa ń wọ Ibi Mímọ́ jùlọ lọ ní ọdọọdún pẹlu ẹ̀jẹ̀ tí kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀. +Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ọpọlọpọ ìgbà ni ìbá ti máa jìyà láti ìgbà tí a ti fi ìdí ayé sọlẹ̀. Ṣugbọn ó fi ara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nígbà tí àkókò òpin dé, láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù nípa ẹbọ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tí ó fi ara rẹ̀ rú. +Dandan ni pé kí gbogbo eniyan kú lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn ikú ìdájọ́ ló kàn. +Bákan náà ni Kristi, nígbà tí a ti fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ lọ, yóo tún pada lẹẹkeji, kì í ṣe láti tún ru ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ṣugbọn láti gba àwọn tí ó ń fi ìtara retí rẹ̀ là. +Lẹ́yìn aṣọ ìkélé keji ni àgọ́ tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ jùlọ wà. +Níbẹ̀ ni pẹpẹ wúrà wà fún sísun turari, ati àpótí majẹmu tí a fi wúrà bò yíká. Ninu àpótí yìí ni apẹ wúrà kékeré kan wà tí wọ́n fi mana sí ninu, ati ọ̀pá Aaroni tí ó rúwé nígbà kan rí, ati àwọn wàláà òkúta tí a kọ òfin mẹ́wàá sí. +Ní òkè àpótí yìí ni àwọn kerubu ògo Ọlọrun wà, tí òjìji wọn bo ìtẹ́ àánú. N kò lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí fínnífínní ní àkókò yìí. +Bí a ti ṣe ṣe ètò gbogbo nǹkan wọnyi nìyí. Ninu àgọ́ àkọ́kàn ni àwọn alufaa ti máa ń ṣe wọlé-wọ̀de nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìsìn wọn. +Ṣugbọn, Olórí Alufaa nìkan ní ó máa ń wọ inú àgọ́ keji. Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún sì ni. Òun náà kò sì jẹ́ wọ ibẹ̀ láì mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, tí yóo fi rúbọ fún ara rẹ̀ ati fún ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn eniyan bá ṣèèṣì dá. +Ẹ̀mí Mímọ́ fihàn nípa èyí pé ọ̀nà ibi mímọ́ kò ì tíì ṣí níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ ekinni bá wà. +Àkàwé ni gbogbo èyí jẹ́ fún àkókò yìí. Àwọn ẹ̀bùn ati ẹbọ tí wọn ń rú nígbà náà kò lè fún àwọn tí ó ń rú wọn ní ìbàlẹ̀ àyà patapata. +Iyawo Hosia ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀. +Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Hosia, ọmọ Beeri nìyí, ní àkókò tí Usaya ati Jotamu, ati Ahasi, ati Hesekaya jọba ní ilẹ̀ Juda; tí Jeroboamu, ọmọ Joaṣi, sì jọba ní ilẹ̀ Israẹli. +Àwọn ọmọ Israẹli yóo pọ̀ sí i bí iyanrìn etí òkun tí kò ṣe é wọ̀n, tí kò sì ṣe é kà. Níbi tí a ti sọ fún wọn pé, “Kì í ṣe eniyan mi”, níbẹ̀ ni a óo ti pè wọ́n ní, “ọmọ Ọlọrun Alààyè.” +A óo kó àwọn eniyan Israẹli ati ti Juda papọ̀, wọn óo yan olórí kanṣoṣo fún ara wọn; wọn óo sì máa ti ibẹ̀ jáde wá. Dájúdájú, ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesireeli yóo jẹ́. +Nígbà tí Ọlọrun kọ́kọ́ bá Israẹli sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosia, Ọlọrun ní, “Lọ fẹ́ obinrin alágbèrè kan, kí o sì bí àwọn ọmọ alágbèrè; nítorí pé àwọn eniyan mi ti ṣe àgbèrè pupọ nípa pé, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀.” +Hosia bá lọ fẹ́ iyawo kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gomeri, ọmọ Dibulaimu. Gomeri lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún un. +OLUWA sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní Jesireeli; nítorí láìpẹ́ yìí ni n óo jẹ ìdílé Jehu níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn tí ó dá ní Jesireeli, n óo sì fi òpin sí ìjọba Israẹli. +Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn ọmọ ogun Israẹli ní àfonífojì Jesireeli.” +Gomeri tún lóyún, ó sì bí ọmọbinrin kan. OLUWA tún sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní, ‘Kò sí Àánú’; nítorí n kò ní ṣàánú àwọn eniyan Israẹli mọ́, +n kò sì ní dáríjì wọ́n mọ́, ṣugbọn n óo fẹ́ràn ilé Juda, n óo sì ṣàánú wọn, èmi OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n là, láìlo ọfà ati ọrun, idà tabi ogun, tabi ẹṣin ati àwọn ẹlẹ́ṣin.” +Lẹ́yìn tí Gomeri gba ọmú lẹ́nu ‘Kò sí Àánú’ ó tún lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. +OLUWA tún sọ fún Hosia pé: “Sọ ọmọ náà ní ‘Kì í ṣe Eniyan Mi’, nítorí pé ẹ̀yin ọmọ Israẹli kì í ṣe eniyan mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọrun yín.” +OLUWA Kéde Ìdájọ́ lórí Israẹli. +Àwọn ọmọ Israẹli dàbí àjàrà dáradára tí ń so èso pupọ. Bí èso rẹ̀ tí ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni pẹpẹ oriṣa wọn ń pọ̀ sí i. Bí àwọn ìlú wọn tí ń dára sí i ni àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn náà ń dára sí i. +N óo dojú kọ àwọn tí ń ṣe ségesège n óo jẹ wọ́n níyà. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ láti kojú wọn, nígbà tí wọ́n bá ń jìyà fún ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. +Efuraimu dàbí ọmọ mààlúù tí a ti fi iṣẹ́ ṣíṣe kọ́, tí ó sì fẹ́ràn láti máa pa ọkà, mo fi ọrùn rẹ̀ tí ó lẹ́wà sílẹ̀; ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbé àjàgà bọ̀ ọ́ lọ́rùn, ó di dandan kí Juda kọ ilẹ̀, kí Israẹli sì máa ro oko fún ara rẹ̀. +Ẹ gbin òdodo fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ẹ lọ dá oko sí ilẹ̀ tí ẹ ti kọ̀ sílẹ̀, nítorí ó tó àkókò láti wá OLUWA, kí ó lè wá rọ ìgbàlà le yín lórí bí òjò. +Ẹ ti gbin ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti ká aiṣododo, ẹ ti jẹ èso ẹ̀tàn.“Nítorí pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun ati ọpọlọpọ ọmọ ogun yín, +nítorí náà, ogun yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn eniyan yín, gbogbo ibi ààbò yín ni yóo parun. Bí Ṣalimani ti pa Betabeli run, ní ọjọ́ ogun, ní ọjọ́ tí wọ́n pa ìyá tòun tọmọ; +bẹ́ẹ̀ ni a óo ṣe si yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí ìwà burúkú yín. Bí ogun bá tí ń bẹ̀rẹ̀ ni a óo ti pa ọba Israẹli run.” +Èké ni wọ́n, nítorí náà wọn óo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, OLUWA yóo wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, yóo sì fọ́ àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn. +Wọn óo máa wí nisinsinyii pé, “A kò ní ọba, nítorí pé a kò bẹ̀rù OLUWA; kí ni ọba kan fẹ́ ṣe fún wa?” +Wọ́n ń fọ́nnu lásán; wọ́n ń fi ìbúra asán dá majẹmu; nítorí náà ni ìdájọ́ ṣe dìde sí wọn bíi koríko olóró, ní poro oko. +Àwọn ará Samaria wárìrì fún ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù, oriṣa ìlú Betafeni. Àwọn eniyan ibẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, àwọn babalóòṣà rẹ̀ yóo pohùnréré ẹkún lé e lórí, nítorí ògo rẹ̀ tí ó ti fò lọ. +Dájúdájú, a óo gbé ère oriṣa náà lọ sí Asiria, a óo fi ṣe owó ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba ńlá ibẹ̀. Ojú yóo ti Efuraimu, ojú yóo sì ti Israẹli nítorí ère oriṣa rẹ̀. +Ọba Samaria yóo parun bí ẹ̀ẹ́rún igi tí ó léfòó lórí omi. +A óo pa ibi pẹpẹ ìrúbọ Afeni, tíí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli run; ẹ̀gún ati òṣùṣú yóo hù jáde lórí àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóo sì sọ fún àwọn òkè gíga pé kí wọ́n bo àwọn mọ́lẹ̀, wọn óo sì sọ fún àwọn òkè kéékèèké pé kí wọ́n wó lu àwọn. +Láti ìgbà Gibea ni Israẹli ti ń dẹ́ṣẹ̀; sibẹ wọn kò tíì jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀. Ṣé ogun kò ní pa wọ́n ní Gibea? +Ìfẹ́ Ọlọrun sí Àwọn Eniyan Rẹ̀, Ọlọ̀tẹ̀. +OLUWA ní,“Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọde, mo fẹ́ràn rẹ̀,láti ilẹ̀ Ijipti ni mo sì ti pe ọmọ mi jáde. +“Àwọn ọmọ Israẹli yóo wá mi, n óo sì bú bíi kinniun; lóòótọ́ n óo bú, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin yóo sì fi ìbẹ̀rùbojo jáde wá láti ìwọ̀ oòrùn; +wọn yóo fi ìbẹ̀rùbojo fò wá bí ẹyẹ láti ilẹ̀ Ijipti, ati bí ẹyẹ àdàbà láti ilẹ̀ Asiria; n óo sì dá wọn pada sí ilé wọn. Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.” +OLUWA ní, “Àwọn ọmọ Efuraimu parọ́ fún mi, ilẹ̀ Israẹli kún fún ẹ̀tàn, sibẹsibẹ mo mọ ilé Juda, nítorí pé ó jẹ́ olóòótọ́ sí èmi, Ẹni Mímọ́. +Ṣugbọn bí mo ti ń pè wọ́n tó,bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń sá fún mi,wọ́n ń rúbọ sí àwọn oriṣa Baali,wọ́n ń sun turari sí ère. +Bẹ́ẹ̀ ni èmi ni mo kọ́ Efuraimu ní ìrìn,mo gbé wọn lé ọwọ́ mi,ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé èmi ni mo wo àwọn sàn. +Mo fà wọ́n mọ́ra pẹlu okùn àánú ati ìdè ìfẹ́,mo dàbí ẹni tí ó tú àjàgà kúrò ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn,mo sì bẹ̀rẹ̀, mo gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn. +“Wọn óo pada sí ilẹ̀ Ijipti, Asiria óo sì jọba lé wọn lórí, nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi. +A óo fi idà run àwọn ìlú wọn, irin ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè wọn yóo ṣẹ́, a óo sì pa wọ́n run ninu ibi ààbò wọn. +Àwọn eniyan mi ti pinnu láti yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí náà n óo ti àjàgà bọ̀ wọ́n lọ́rùn, kò sì ní sí ẹni tí yóo bá wọn bọ́ ọ. +“Mo ha gbọdọ̀ yọwọ́ lọ́rọ̀ yín ẹ̀yin Efuraimu?Mo ha gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Israẹli?Mo ha gbọdọ̀ pa ọ́ run bí mo ti pa Adimai run;kí n ṣe sí ọ bí mo ti ṣe sí Seboimu?Ọkàn mi kò gbà á,àánú yín a máa ṣe mí. +N kò ní fa ibinu yọ mọ́,n kò ní pa Efuraimu run mọ́,nítorí pé Ọlọrun ni mí,n kì í ṣe eniyan,èmi ni Ẹni Mímọ́ tí ó wà láàrin yín,n kò sì ní pa yín run. +Àwọn Ìdájọ́ Mìíràn. +“Asán ati ìbàjẹ́ ni gbogbo nǹkan tí Efuraimu ń ṣe látàárọ̀ dalẹ́. Wọ́n ń parọ́ kún irọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ipá wọn ń pọ̀ sí i. Wọ́n ń bá àwọn Asiria dá majẹmu, wọ́n sì ń ru òróró lọ sí ilẹ̀ Ijipti.” +“Mo bá àwọn wolii sọ̀rọ̀; èmi ni mo fi ọpọlọpọ ìran hàn wọ́n, tí mo sì tipasẹ̀ wọn pa ọpọlọpọ òwe. +Ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà wà ní Gileadi, dájúdájú yóo parun; bí wọ́n bá fi akọ mààlúù rúbọ ní Giligali, pẹpẹ wọn yóo dàbí òkúta tí a kójọ ní poro oko.” +Jakọbu sálọ sí ilẹ̀ Aramu, níbẹ̀ ni ó ti singbà, tí ó ṣiṣẹ́ darandaran, nítorí iyawo tí ó fẹ́. +Nípasẹ̀ wolii kan ni OLUWA ti mú Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, nípasẹ̀ wolii kan ni a sì ti pa á mọ́. +Efuraimu ti mú èmi, OLUWA rẹ̀ bínú lọpọlọpọ, nítorí náà, n óo da ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lé e lórí, òun tí ó gàn mí ni yóo di ẹni ẹ̀gàn. +OLUWA ní ẹjọ́ tí yóo bá àwọn ọmọ Juda rò, yóo jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà gẹ́gẹ́ bí ìwà wọn, yóo sì san ẹ̀san iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún wọn. +Jakọbu, baba ńlá wọn di arakunrin rẹ̀ ní gìgísẹ̀ mú ninu oyún, nígbà tí ó dàgbà tán, ó bá Ọlọrun wọ̀jàkadì. +Ó bá angẹli jà, ó ja àjàṣẹ́gun, ó sọkún, ó sì wá ojurere rẹ̀. Ó bá Ọlọrun pàdé ní Bẹtẹli, níbẹ̀ ni Ọlọrun sì ti bá a sọ̀rọ̀. +OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, OLUWA ni orúkọ rẹ̀: +Nítorí náà, ẹ yipada nípa agbára Ọlọrun yín, ẹ di ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo mú, kí ẹ sì dúró de Ọlọrun yín nígbà gbogbo. +OLUWA ní, “Efuraimu jẹ́ oníṣòwò tí ó gbé òṣùnwọ̀n èké lọ́wọ́, ó sì fẹ́ràn láti máa ni eniyan lára. +Efuraimu ní, ‘Mo ní ọrọ̀, mo ti kó ọrọ̀ jọ fún ara mi, ṣugbọn gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ kò lè mú ẹ̀bi rẹ̀ kúrò.’ +Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ láti ilẹ̀ Ijipti; n óo tún mú ọ pada gbé inú àgọ́, bí àwọn ọjọ́ àjọ ìyàsọ́tọ̀. +Paríparí Ìdájọ́ Israẹli. +Tẹ́lẹ̀ rí, bí ẹ̀yà Efuraimu bá sọ̀rọ̀, àwọn eniyan a máa wárìrì; wọ́n níyì láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù, ṣugbọn nítorí pé wọ́n bọ oriṣa Baali, wọ́n dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì kú. +Níbo ni ọba yín wà nisinsinyii, tí yóo gbà yín là? Níbo ni àwọn olórí yín wà, tí wọn yóo gbèjà yín? Àwọn tí ẹ bèèrè fún, tí ẹ ní, ‘Ẹ fún wa ní ọba ati àwọn ìjòyè.’ +Pẹlu ibinu, ni mo fi fun yín ní àwọn ọba yín, ìrúnú ni mo sì fi mú wọn kúrò. +“A ti di ẹ̀ṣẹ̀ Efuraimu ní ìtí ìtí, a ti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pamọ́. +Àwọn ọmọ Israẹli ní anfaani láti wà láàyè, ṣugbọn ìwà òmùgọ̀ wọn kò jẹ́ kí wọ́n lo anfaani náà. Ó dàbí ọmọ tí ó kọ̀, tí kò jáde kúrò ninu ìyá rẹ̀ ní àkókò ìrọbí. +N kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú, n kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ ikú. Ikú! Níbo ni àjàkálẹ̀ àrùn rẹ wà? Ìwọ isà òkú! Ìparun rẹ dà? Àánú kò sí lójú mi mọ́. +Bí Israẹli tilẹ̀ rúwé bí ewéko etí odò, atẹ́gùn OLUWA láti ìlà oòrùn yóo fẹ́ wá, yóo wá láti inú aṣálẹ̀; orísun rẹ̀ yóo gbẹ, ojú odò rẹ̀ yóo sì gbẹ pẹlu; a óo kó ìṣúra ati ohun èlò olówó iyebíye rẹ̀ kúrò. +Samaria ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi Ọlọrun rẹ̀, ogun ni yóo pa wọ́n, a óo ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, a óo sì la inú àwọn aboyún wọn.” +Nisinsinyii, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yá ère fún ara wọn; ère fadaka, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan, Wọ́n ń sọ pé, “Ẹ wá rúbọ sí i.” Eniyan wá ń fi ẹnu ko ère mààlúù lẹ́nu! +Nítorí náà, wọn óo dàbí ìkùukùu òwúrọ̀, ati bí ìrì tíí máa ń yára gbẹ, wọ́n óo dàbí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kúrò ní ibi ìpakà, ati bí èéfín tí ń jáde láti ojú fèrèsé. +OLUWA ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, láti ìgbà tí ẹ ti wà ní ilẹ̀ Ijipti: ẹ kò ní Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ní olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi. +Èmi ni mo ṣe ìtọ́jú yín nígbà tí ẹ wà ninu aṣálẹ̀, ninu ilẹ̀ gbígbẹ; +ṣugbọn nígbà tí ẹ jẹun yó tán, ẹ̀ ń gbéraga, ẹ gbàgbé mi. +Nítorí náà, bíi kinniun ni n óo ṣe si yín, n óo lúgọ lẹ́bàá ọ̀nà bí àmọ̀tẹ́kùn; +n óo yọ si yín bí ẹranko beari tí wọ́n kó lọ́mọ lọ, n óo sì fa àyà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. N óo ya yín jẹ bíi kinniun, bí ẹranko burúkú ṣe ń fa ẹran ya. +“N óo pa yín run, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; ta ni yóo ràn yín lọ́wọ́? +Ẹ̀bẹ̀ Hosia fún Israẹli. +Ẹ pada tọ OLUWA Ọlọrun yín lọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ ti kọsẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. +Ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, kí ẹ sọ pé, “Mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, gba ohun tí ó dára a óo sì máa yìn ọ́ lógo. +Asiria kò lè gbà wá là, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gun ẹṣin; a kò sì ní pe oriṣa, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wa, ní Ọlọrun wa mọ́. OLUWA, ìwọ ni ò ń ṣàánú fún ọmọ tí kò lẹ́nìkan.” +Ọlọrun ní,“N óo gba ìwà aiṣootọ lọ́wọ́ wọn,n óo fẹ́ wọn tọkàntọkàn,nítorí n kò bínú sí wọn mọ́. +Bí ìrì ni n óo máa sẹ̀ sí Israẹli,ẹwà rẹ̀ yóo yọ bí òdòdó lílì,gbòǹgbò rẹ̀ yóo sì múlẹ̀ bíi gbòǹgbò igi kedari Lẹbanoni. +Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo tàn kálẹ̀;ẹwà rẹ̀ yóo yọ bíi ti igi olifi,òórùn rẹ̀ yóo sì dàbí ti igi Lẹbanoni. +Wọn óo pada sábẹ́ ààbò mi,wọn óo rúwé bí igi inú ọgbà;wọn óo sì tanná bí àjàrà,òórùn wọn óo dàbí ti waini Lẹbanoni. +Efuraimu yóo sọ pé, ‘kí ni mo ní ṣe pẹlu àwọn oriṣa?’Nítorí èmi ni n óo máa gbọ́ adura rẹ̀,tí n óo sì máa tọ́jú rẹ̀.Mo dàbí igi sipirẹsi tí kì í wọ́wé tòjò tẹ̀ẹ̀rùn.Lọ́dọ̀ mi ni èso rẹ̀ ti ń wá.” +Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́n, kí ó mọ àwọn nǹkan wọnyi; kí òye rẹ̀ sì yé ẹnikẹ́ni tí ó bá lóye; nítorí pé ọ̀nà OLUWA tọ́, àwọn tí wọ́n bá dúró ṣinṣin ni yóo máa tọ̀ ọ́, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kọsẹ̀ níbẹ̀. +Gomeri Alaiṣootọ–Israẹli Alaiṣootọ. +Pe arakunrin rẹ ní “Eniyan mi” kí o sì pe arabinrin rẹ ní “Ẹni tí ó rí àánú gbà.” +N óo tú u sí ìhòòhò lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi. +N óo fi òpin sí ayọ̀ rẹ̀ ati ọjọ́ àsè rẹ̀, ọjọ́ oṣù tuntun rẹ̀, ọjọ́ ìsinmi rẹ̀, ati gbogbo àjọ̀dún tí ó ti yà sọ́tọ̀. +N óo run gbogbo igi àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, àwọn ohun tí ó ń pè ní owó ọ̀yà, tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ san fún un. N óo sọ ọgbà rẹ̀ di igbó, àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo sì jẹ wọ́n ní àjẹrun. +N óo jẹ ẹ́ níyà fún àwọn ọjọ́ tí ó yà sọ́tọ̀, tí ó fi ń sun turari sí àwọn oriṣa Baali, tí ó kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ sára, tí ó ń sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, tí ó sì gbàgbé mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Nítorí náà, n óo tàn án lọ sinu aṣálẹ̀, n óo bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. +N óo sì fún un ní àwọn ọgbà àjàrà rẹ̀ pada níbẹ̀, n óo sì sọ àfonífojì Akori di Ẹnu Ọ̀nà Ìrètí. Yóo kọrin fún mi bí ó tí ń ṣe ní ìgbà èwe rẹ̀, nígbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Ijipti dé. +OLUWA ní, nígbà tí ó bá yá, yóo máa pè mí ní ọkọ rẹ̀, kò ní pè mí ní Baali rẹ̀ mọ́. +Nítorí pé, n óo gba orúkọ Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀, kò sì ní dárúkọ rẹ̀ mọ́. +Nígbà náà ni n óo tìtorí tirẹ̀ bá àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn nǹkan tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ dá majẹmu, n óo sì mú ọfà, idà, ati ogun kúrò ní ilẹ̀ náà. N óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ní alaafia ati ní àìléwu. +Ìwọ Israẹli, n óo sọ ọ́ di iyawo mi títí lae;n óo sọ ọ́ di iyawo mi lódodo ati lótìítọ́,ninu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati àánú. +Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ bá ìyá yín sọ̀rọ̀; nítorí pé kì í ṣe aya mi mọ́, ati pé èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀ mọ́. Ẹ sọ fún un pé kí ó má ṣe àgbèrè mọ́, kí ó sì fi ìṣekúṣe rẹ̀ sílẹ̀. +N óo sọ ọ́ di iyawo mi, lótìítọ́, o óo sì mọ̀ mí ní OLUWA. +OLUWA ní,“Ní ọjọ́ náà, n óo dáhùn adura ojú ọ̀run,ojú ọ̀run yó sì dáhùn adura ilẹ̀. +Ilẹ̀ yóo sì dáhùn adura ọkà, ati ti waini ati ti òróró.Àwọn náà óo sì dáhùn adura Jesireeli. +N óo fi ìdí àwọn eniyan mi múlẹ̀ ní ilẹ̀ náà,wọn yóo sì máa bí sí i.N óo ṣàánú ẹni tí a tí ń pè ní ‘Kò sí àánú’,n óo sì sọ fún ẹni tí a tí ń pè ní ‘Kì í ṣe eniyan mi’ pé eniyan mi ni;òun náà yóo sì dá mi lóhùn pé,‘Ìwọ ni Ọlọrun mi.’ ” +Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo tú u sí ìhòòhò, n óo ṣe é bí ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí i. N óo ṣe é bí aṣálẹ̀, àní, bí ilẹ̀ tí ó gbẹ, n óo sì fi òùngbẹ gbẹ ẹ́ pa. +N kò ní ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n. +Nítorí alágbèrè ni ìyá wọn, ẹni tí ó bí wọn sì ti hùwà ainitiju. Òun fúnrarẹ̀ sọ pé, “N óo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ mi, àwọn tí wọn ń fún mi ní oúnjẹ ati omi, ati aṣọ òtútù, ati aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, ati òróró olifi ati ọtí.” +Nítorí náà, n óo fi ẹ̀gún ṣe ọgbà yí i ká; n óo mọ odi yí i ká, tí kò fi ní rí ọ̀nà jáde. +Yóo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kò ní lè bá wọn; yóo wá wọn káàkiri pẹlu ìtara, ṣugbọn kò ní rí wọn. Yóo wá wí nígbà náà pé, “N óo pada sọ́dọ̀ ọkọ mi àárọ̀, nítorí ó dára fún mi lọ́dọ̀ rẹ̀ ju ti ìsinsìnyìí lọ.” +Kò gbà pé èmi ni mo fún òun ní oúnjẹ, tí mo fún un ní waini ati òróró, tí mo sì fún un ní ọpọlọpọ fadaka ati wúrà tí ó ń lò fún oriṣa Baali. +Nítorí náà n óo gba waini ati ọkà mi pada ní àkókò wọn, n óo sì gba aṣọ òtútù ati ẹ̀wù fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun mi, tí kì bá fi bo ìhòòhò rẹ̀. +Hosia ati Obinrin Alaiṣootọ. +OLUWA tún sọ fún mi pé: “Lọ fẹ́ aya tí ń ṣe àgbèrè pada, kí o fẹ́ràn rẹ̀, bí mo ti fẹ́ràn Israẹli, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n yipada sí ọlọrun mìíràn, wọ́n sì fẹ́ràn láti máa jẹ àkàrà tí ó ní èso resini ninu.” +Nítorí náà, mo rà á ní ṣekeli fadaka mẹẹdogun ati ìwọ̀n ọkà baali kan. +Mo sì sọ fún un pé, “O gbọdọ̀ wà fún èmi nìkan fún ọjọ́ gbọọrọ láìṣe àgbèrè, láì sì lọ fẹ́ ọkunrin mìíràn; èmi náà yóo sì jẹ́ tìrẹ nìkan.” +Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli yóo wà fún ọjọ́ gbọọrọ láìní ọba tabi olórí láìsí ẹbọ tabi ère, láìsí aṣọ efodu tabi ère terafimu. +Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Israẹli yóo pada tọ OLUWA Ọlọrun wọn, ati Dafidi, ọba wọn lọ. Wọn yóo fi ìbẹ̀rù wá sọ́dọ̀ OLUWA, wọn yóo sì gba oore rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn. +OLUWA Fi Ẹ̀sùn Kan Israẹli. +Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; OLUWA fi ẹ̀sùn kan gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé, “Kò sí òtítọ́, tabi àánú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ Ọlọrun ní ilẹ̀ náà, +Ẹ óo máa jẹun, ṣugbọn ẹ kò ní yó; Ẹ óo máa ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ṣugbọn ẹ kò ní pọ̀ sí i; nítorí ẹ ti kọ èmi Ọlọrun sílẹ̀ ẹ sì yipada sí ìwà ìbọkúbọ.” +OLUWA ní, “Ọtí waini ati waini tuntun ti ra àwọn eniyan mi níyè. +Wọ́n ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ igi gbígbẹ́, ọ̀pá wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wọn. Ẹ̀mí àgbèrè ẹ̀sìn ti mú wọn ṣáko, wọ́n ti kọ Ọlọrun wọn sílẹ̀ láti máa bọ ìbọkúbọ. +Wọ́n ń rúbọ lórí òkè gíga, wọ́n ń sun turari lórí òkè kéékèèké, ati lábẹ́ igi oaku, ati igi populari ati igi terebinti, nítorí òjìji abẹ́ wọn tutù. Nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin yín ṣe di aṣẹ́wó, àwọn aya yín sì di alágbèrè. +Ṣugbọn n kò ní jẹ àwọn ọmọbinrin yín níyà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe aṣẹ́wó, tabi kí n jẹ àwọn aya yín níyà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè; nítorí pé, àwọn ọkunrin yín pàápàá ń bá àwọn aṣẹ́wó lòpọ̀, wọ́n sì ń bá àwọn aṣẹ́wó ilé oriṣa rúbọ. Àwọn tí wọn kò bá ní ìmọ̀ yóo sì parun. +“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ìwọ Israẹli, má kó ẹ̀bi bá Juda. Má wọ Giligali lọ b��̣rìṣà, má sì gòkè lọ sí Betafeni, má sì lọ búra níbẹ̀ pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ.’ +Israẹli ń ṣe agídí bí ọ̀dọ́ mààlúù tí ó ya olóríkunkun; ṣe OLUWA lè máa bọ́ wọn bí aguntan nisinsinyii lórí pápá tí ó tẹ́jú. +Ìbọ̀rìṣà ti wọ Efuraimu lẹ́wù, ẹ fi wọ́n sílẹ̀. +Ẹgbẹ́ ọ̀mùtí ni wọ́n, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àgbèrè, ìtìjú yá wọn lára ju ògo lọ. +Afẹ́fẹ́ yóo gbá wọn lọ, ojú ìsìn ìbọ̀rìṣà wọn yóo sì tì wọ́n. +àfi ìbúra èké ati irọ́ pípa; ìpànìyàn, olè jíjà ati àgbèrè ni ó pọ̀ láàrin wọn. Wọ́n ń yẹ àdéhùn, wọ́n ń paniyan léraléra. +Nítorí náà, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ ń jìyà, àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn ẹja sì ń ṣègbé.” +Ọlọrun ní, Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jiyàn, ẹ kò sì gbọdọ̀ ka ẹ̀sùn sí ẹnikẹ́ni lẹ́sẹ̀, nítorí pé ẹ̀yin alufaa gan-an ni mò ń fi ẹ̀sùn kàn. +Nítorí ẹ óo fẹsẹ̀ kọ lojumọmọ, ẹ̀yin wolii pàápàá yóo kọsẹ̀ lóru, n óo sì pa Israẹli, ìyá yín run. +Àwọn eniyan mi ń ṣègbé nítorí àìsí ìmọ̀; nítorí pé ẹ̀yin alufaa ti kọ ìmọ̀ mi sílẹ̀, èmi náà yóo kọ̀ yín ní alufaa mi. Nítorí pé ẹ ti gbàgbé òfin Ọlọrun yín, èmi náà yóo gbàgbé àwọn ọmọ yín. +“Bí ẹ̀yin alufaa ti ń pọ̀ sí i, ni ẹ̀ṣẹ̀ yín náà ń pọ̀ sí i, n óo yí ògo wọn pada sí ìtìjú. +Ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi wá oúnjẹ fún ara yín, ẹ sì ń mú kí wọ́n máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ +Ìyà kan náà ni ẹ̀yin alufaa ati àwọn eniyan yóo jẹ, n óo jẹ yín níyà nítorí ìwà burúkú yín, n óo sì gbẹ̀san lára yín nítorí ìṣe yín. +Ìkìlọ̀ Hosia nípa Ìwà Ìbọ̀rìṣà. +“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin alufaa! Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli ati ẹ̀yin ìdílé ọba! Ẹ̀yin ni ìdájọ́ náà dé bá; nítorí ẹ dàbí tàkúté ní Misipa, ati bí àwọ̀n tí a ta sílẹ̀ lórí òkè Tabori. +OLUWA wí pé: “Àwọn olórí ní Juda dàbí àwọn tí wọn ń yí ààlà ilẹ̀ pada, n óo da ibinu mi sórí wọn, bí ẹni da omi. +Ìyà ń jẹ Efuraimu, ìdájọ́ ìparun sì ti dé bá a, nítorí pé, ó ti pinnu láti máa tẹ̀lé ohun asán. +Nítorí náà, mo dàbí kòkòrò ajẹnirun sí Efuraimu, ati bí ìdíbàjẹ́ sí Juda. +“Nígbà tí Efuraimu rí àìsàn rẹ̀, tí Juda sì rí ọgbẹ́ rẹ̀, Efuraimu sá tọ Asiria lọ, ó sì ranṣẹ sí ọba ńlá ibẹ̀. Ṣugbọn kò lè wo àìsàn Israẹli tabi kí ó wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn. +Bíi kinniun ni n óo rí sí Efuraimu, n óo sì fò mọ́ Juda bí ọ̀dọ́ kinniun. Èmi fúnra mi ni n óo fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, n óo sì kúrò níbẹ̀. N óo kó wọn lọ, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà wọ́n sílẹ̀. +“N óo pada sí ibùgbé mi títí wọn yóo fi mọ ẹ̀bi wọn, tí wọn yóo sì máa wá mi nígbà tí ojú bá pọ́n wọn.” +Wọ́n ti gbẹ́ kòtò jíjìn ní ìlú Ṣitimu; ṣugbọn n óo jẹ wọ́n níyà. +Mo mọ Efuraimu, bẹ́ẹ̀ ni Israẹli kò ṣàjèjì sí mi; nisinsinyii, ìwọ Efuraimu ti ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, Israẹli sì ti di aláìmọ́.” +Gbogbo ibi tí wọn ń ṣe, kò jẹ́ kí wọ́n lè pada sọ́dọ̀ Ọlọrun wọn, nítorí pé ọkàn wọn kún fún ẹ̀mí àgbèrè, wọn kò sì mọ OLUWA. +Ìgbéraga Israẹli hàn kedere lójú rẹ̀; Efuraimu yóo kọsẹ̀, yóo sì ṣubú ninu ìwà burúkú rẹ̀, Juda náà yóo ṣubú pẹlu wọn. +Wọn yóo mú mààlúù ati aguntan wá, láti fi wá ojurere OLUWA, ṣugbọn wọn kò ní rí i; nítorí pé, ó ti fi ara pamọ́ fún wọn. +Wọ́n ti hùwà aiṣootọ sí OLUWA; nítorí pé wọ́n ti bí ọmọ àjèjì. Oṣù tuntun ni yóo run àtàwọn, àtoko wọn. +Ẹ fọn fèrè ní Gibea, ẹ fọn fèrè ogun ní Rama, ẹ pariwo ogun ní Betafeni, ogun dé o, ẹ̀yin ará Bẹnjamini! +Efuraimu yóo di ahoro ní ọjọ́ ìjìyà; mo ti fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ dájúdájú hàn, láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli. +Àwọn Eniyan náà Ṣe Ìrònúpìwàdà Èké. +Wọn óo wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pada sọ́dọ̀ OLUWA; nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti fà wá ya, sibẹ yóo wò wá sàn; ó ti pa wá lára lóòótọ́, ṣugbọn yóo di ọgbẹ́ wa. +Mo rí ohun tí ó burú gan-an ní Israẹli; ìbọ̀rìṣà Efuraimu wà níbẹ̀, Israẹli sì ti ba ara wọn jẹ́. +“Ẹ̀yin ará Juda pàápàá, mo ti dá ọjọ́ ìjìyà yín sọ́nà, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dá. +Lẹ́yìn ọjọ́ meji, yóo sọ wá jí, ní ọjọ́ kẹta, yóo gbé wa dìde, kí á lè wà láàyè níwájú rẹ̀. +Ẹ jẹ́ kí á mọ̀ ọ́n, ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú kí á mọ OLUWA. Dídé rẹ̀ dájú bí àfẹ̀mọ́jú; yóo sì pada wá sọ́dọ̀ wa bí ọ̀wààrà òjò, ati bí àkọ́rọ̀ òjò tí ń bomirin ilẹ̀.” +Ṣugbọn OLUWA wí pé, “Kí ni kí n ti ṣe ọ́ sí, ìwọ Efuraimu? Kí ni kí n ti ṣe ọ́ sí, ìwọ Juda? Ìfẹ́ yín dàbí ìkùukùu òwúrọ̀, ati bí ìrì tíí yára á gbẹ. +Nítorí náà ni mo fi jẹ́ kí àwọn wolii mi ké wọn lulẹ̀, mo ti fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi pa wọ́n, ìdájọ́ mi sì yọ bí ìmọ́lẹ̀. +Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú; ìmọ̀ Ọlọrun ni mo bèèrè, kì í ṣe ẹbọ sísun. +“Ṣugbọn wọ́n yẹ àdéhùn tí mo bá wọn ṣe, bí Adamu, wọ́n hùwà aiṣododo sí èmi Ọlọrun. +Gileadi ti di ìlú àwọn ẹni ibi, ó kún fún ìpànìyàn. +Bí àwọn ọlọ́ṣà tií ba de eniyan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn alufaa kó ara wọn jọ, láti paniyan ní ọ̀nà Ṣekemu, wọ́n ń ṣe nǹkan ìtìjú láìbìkítà. +Ọ̀tẹ̀ ní Ààfin. +“Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ire Israẹli eniyan mi pada, tí mo bá sì fẹ́ wò wọ́n sàn, kìkì ìwà ìbàjẹ́ Efuraimu ati ìwà ìkà Samaria ni mò ń rí; nítorí pé ìwà aiṣododo ni wọ́n ń hù. Àwọn olè ń fọ́lé, àwọn jàgùdà sì ń jalè ní ìgboro. +Ìgbéraga àwọn ọmọ Israẹli ń takò wọ́n, sibẹsibẹ wọn kò pada sọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun wọn, tabi kí wọ́n tilẹ̀ wá a nítorí gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe. +Efuraimu dàbí ẹyẹ àdàbà, ó jẹ́ òmùgọ̀ ati aláìlóye, ó ń pe Ijipti fún ìrànlọ́wọ́, o ń sá tọ Asiria lọ. +Ṣugbọn bí wọn tí ń lọ, n óo da àwọ̀n lé wọn lórí, n óo mú wọn bí ẹyẹ ojú ọ̀run; n óo sì jẹ wọ́n níyà fún ìwà burúkú wọn. +“Wọ́n gbé, nítorí pé wọ́n ti ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun yóo kọlù wọ́n, nítorí pé wọ́n ń bá mi ṣọ̀tẹ̀! Ǹ bá rà wọ́n pada, ṣugbọn wọ́n ń parọ́ mọ́ mi. +Wọ́n ń sọkún lórí ibùsùn wọn, ṣugbọn ẹkún tí wọn ń sun sí mi kò ti ọkàn wá; nítorí oúnjẹ ati ọtí waini ni wọ́n ṣe ń gbé ara ṣánlẹ̀; ọ̀tẹ̀ ni wọ́n ń bá mi ṣe. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, èmi ni mo tọ́ wọn dàgbà, tí mo sì fún wọn lókun, sibẹsibẹ wọ́n ń gbèrò ibi sí mi. +Wọ́n yipada sí oriṣa Baali, wọ́n dàbí ọrun tí ó wọ́, idà ni a óo fi pa àwọn olórí wọn, nítorí ìsọkúsọ ẹnu wọn. Nítorí náà, wọn óo ṣẹ̀sín ní ilẹ̀ Ijipti.” +Ṣugbọn wọn kò rò ó pé mò ń ranti gbogbo ìwà burúkú àwọn. Ìwà burúkú wọn yí wọn ká, ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì wà níwájú mi.” +OLUWA wí pé, “Àwọn eniyan ń dá ọba ninu dùn, nípa ìwà ibi wọn, wọ́n ń mú àwọn ìjòyè lóríyá nípa ìwà ẹ̀tàn wọn. +Alágbèrè ni gbogbo wọn; wọ́n dàbí iná ààrò burẹdi tí ó gbóná, tí ẹni tí ń ṣe burẹdi kò koná mọ́, láti ìgbà tí ó ti po ìyẹ̀fun títí tí ìyẹ̀fun náà fi wú. +Ní ọjọ́ tí ọba ń ṣe àjọyọ̀, àwọn ìjòyè mu ọtí àmupara, títí tí ara wọn fi gbóná; ọba pàápàá darapọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́yà. +Iná ọ̀tẹ̀ wọn ń jò bí iná ojú ààrò, inú wọn ń ru, ó ń jó bí iná ní gbogbo òru; ní òwúrọ̀, ó ń jó lálá bí ahọ́n iná. +“Gbogbo wọn gbóná bí ààrò, wọ́n pa àwọn olórí wọn, gbogbo ọba wọn ni wọ́n ti pa léraléra, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ó ké pè mí.” +OLUWA ní, “Efuraimu darapọ̀ mọ́ àwọn eniyan tí wọ́n yí wọn ká, Efuraimu dàbí àkàrà tí kò jinná dénú. +Àwọn àjèjì ti gba agbára rẹ̀, sibẹsibẹ kò mọ̀; orí rẹ̀ kún fún ewú, sibẹsibẹ kò mọ̀. +OLUWA Bá Israẹli Wí nítorí Ìwà Ìbọ̀rìṣà. +OLUWA ní: “Ẹ ti fèrè bọnu, nítorí ẹyẹ igún wà lórí ilé mi, nítorí pé wọ́n ti yẹ àdéhùn tí mo bá wọn ṣe, wọ́n sì ti rú òfin mi. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, n óo kó wọn jọ láìpẹ́, láti jẹ wọ́n níyà, fún ìgbà díẹ̀, lọ́dọ̀ àwọn ọba alágbára tí yóo ni wọ́n lára. +“Nítorí Efuraimu ti tẹ́ ọpọlọpọ pẹpẹ láti dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀, wọ́n ti di pẹpẹ ẹ̀ṣẹ̀ dídá fún un. +Bí mo tilẹ̀ kọ òfin mi sílẹ̀ ní ìgbà ẹgbẹrun, sibẹsibẹ wọn óo kà wọ́n sí nǹkan tó ṣàjèjì. +Wọ́n fẹ́ràn ati máa rúbọ; wọ́n ń fi ẹran rúbọ, wọ́n sì ń jẹ ẹ́; ṣugbọn inú OLUWA kò dùn sí wọn. Yóo wá ranti àìdára wọn nisinsinyii, yóo sì jẹ wọ́n níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn; wọn óo sì pada sí Ijipti. +“Àwọn ọmọ Israẹli ti gbàgbé Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n sì ti kọ́ ààfin fún ara wọn. Àwọn ọmọ Juda ti kọ́ ọpọlọpọ ìlú olódi sí i; ṣugbọn n óo sọ iná sí àwọn ìlú wọn, yóo sì jó àwọn ibi ààbò wọn ní àjórun.” +Wọ́n ń ké pè mí, wọ́n ń wí pé, ‘Ọlọrun wa, àwa ọmọ Israẹli mọ̀ ọ́.’ +Israẹli ti kọ ohun rere sílẹ̀; nítorí náà, àwọn ọ̀tá yóo máa lépa wọn. +“Wọ́n ń fi ọba jẹ, láìsí àṣẹ mi. Wọ́n ń yan àwọn aláṣẹ, ṣugbọn n kò mọ̀ nípa rẹ̀. Wọ́n ń fi fadaka ati wúrà wọn yá ère fún ìparun ara wọn. +Mo kọ oriṣa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù yín, ẹ̀yin ará Samaria. Inú mi ń ru sí wọn. Yóo ti pẹ́ tó kí àwọn ọmọ Israẹli tó di mímọ́? +Oriṣa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kì í ṣe Ọlọrun, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni, a óo sì rún ti Samaria wómúwómú. +Wọ́n ń gbin afẹ́fẹ́, wọn yóo sì ká ìjì líle. Ọkà tí kò bá tú, kò lè lọ́mọ, bí wọ́n bá tilẹ̀ lọ́mọ, tí wọ́n sì gbó, àwọn àjèjì ni yóo jẹ ẹ́ run. +A ti tú Israẹli ká, wọ́n ti kọ́ àṣàkaṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà láàrin wọn, wọ́n sì dàbí ohun èlò tí kò wúlò. +Nítorí pé wọ́n lọ sí Asiria, wọ́n dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ tí ń dá rìn; Efuraimu ti bẹ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́wẹ̀ fún ààbò. +Hosia Kéde Ìjìyà fún Israẹli. +Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ má yọ̀, ẹ sì má dá ara yín ninu dùn, bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nítorí ẹ ti kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, ẹ ti ṣe àgbèrè ẹ̀sìn lọ sọ́dọ̀ oriṣa. Inú yín ń dùn sí owó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ibi ìpakà yín. +OLUWA wí pé: “Mo rí Israẹli he bí ìgbà tí eniyan rí èso àjàrà he ninu aṣálẹ̀. Lójú mi, àwọn baba ńlá yín dàbí èso tí igi ọ̀pọ̀tọ́ kọ́ so ní àkókò àkọ́so rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rí sí mi, ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé òkè Baali Peori, wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ fún oriṣa Baali, wọ́n sì di ohun ẹ̀gbin, bí oriṣa tí wọ́n fẹ́ràn. +Ògo Efuraimu yóo fò lọ bí ẹyẹ, wọn kò ní lóyún, wọn kò ní bímọ, bẹ́ẹ̀ ni ọlẹ̀ kò ní sọ ninu wọn! +Bí wọ́n bá tilẹ̀ bímọ, n óo pa wọ́n tí kò ní ku ẹyọ kan. Bí mo bá kọ̀ wọ́n sílẹ̀, wọ́n gbé!” +Mo rí àwọn ọmọ Efuraimu bí ẹran àpajẹ; Efuraimu gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún pípa. +Fún wọn ní nǹkankan, OLUWA, OLUWA, kí ni ò bá tilẹ̀ fún wọn? Jẹ́ kí oyún máa bàjẹ́ lára obinrin wọn, kí ọmú wọn sì gbẹ. +OLUWA ní, “Gbogbo ìwà burúkú wọn wà ní Giligali, ibẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra wọn. Nítorí iṣẹ́ burúkú wọn, n óo lé wọn jáde ní ilé mi. N kò ní fẹ́ràn wọn mọ́, ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo àwọn olórí wọn. +Ìyà jẹ Efuraimu, gbòǹgbò wọn ti gbẹ, wọn kò sì ní so èso mọ́. Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ, n óo pa àwọn ọmọ tí wọ́n fẹ́ràn.” +Ọlọrun mi yóo pa wọ́n run, nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀; wọn yóo di alárìnkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. +Ọkà ibi ìpakà yín ati ọtí ibi ìpọntí yín kò ní to yín, kò sì ní sí waini tuntun mọ́. +Àwọn ọmọ Israẹli kò ní dúró ní ilẹ̀ OLUWA mọ́; Efuraimu yóo pada sí Ijipti, wọn yóo sì jẹ ohun àìmọ́ ní ilẹ̀ Asiria. +Wọn kò ní rú ẹbọ ohun mímu sí OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ wọn kò ní tẹ́ ẹ lọ́rùn. Oúnjẹ wọn yóo dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, àwọn tí wọ́n bá jẹ ninu rẹ̀ yóo di aláìmọ́. Ebi nìkan ni oúnjẹ wọn yóo wà fún, wọn kò ní mú wá fi rúbọ lára rẹ̀ ní ilé OLUWA. +Kí ni wọn óo ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, kí ni wọn óo ṣe ní ọjọ́ àsè OLUWA? +Wọn yóo fọ́nká lọ sí Asiria; Ijipti ni yóo gbá wọn jọ, Memfisi ni wọn yóo sin wọ́n sí, Ẹ̀gún ọ̀gàn ni yóo hù bo àwọn nǹkan èlò fadaka olówó iyebíye wọn, ẹ̀gún yóo sì hù ninu àgọ́ wọn. +Àkókò ìjìyà ati ẹ̀san ti dé, Israẹli yóo sì mọ̀. Ẹ̀ ń wí pé, “Òmùgọ̀ ni wolii, aṣiwèrè sì ni ẹni tí ó wà ninu ẹ̀mí,” nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yín, ati ìkórìíra yín tí ó pọ̀. +Wolii ni aṣọ́nà fún Efuraimu, àwọn eniyan Ọlọrun mi, sibẹsibẹ tàkúté àwọn pẹyẹpẹyẹ wà lójú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ìkórìíra sì wà ní ilé Ọlọrun rẹ̀. +Wọ́n ti sọ ara wọn di aláìmọ́ lọpọlọpọ, bí ìgbà tí wọ́n wà ní Gibea. Ọlọrun yóo ranti àìdára tí wọ́n ṣe, yóo sì jẹ wọ́n níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. +OLUWA Bá Àwọn Eniyan Rẹ̀ Wí. +Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Juda ati Jerusalẹmu nìyí, nígbà ayé Usaya, Jotamu, Ahasi, ati Hesekaya, àwọn ọba Juda. +Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA,ẹ̀yin ìjòyè Sodomu:Ẹ fetí sí ẹ̀kọ́ Ọlọrun wa,ẹ̀yin ará Gomora +OLUWA ní,“Kí ni gbogbo ẹbọ yín jámọ́ fún mi?Àgbò tí ẹ fi ń rú ẹbọ sísun sí mi ti tó gẹ́ẹ́;bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀rá ẹran àbọ́pa.N kò ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ mààlúù tabi ti ọ̀dọ́ aguntan tabi ti òbúkọ. +Nígbà tí ẹ bá wá jọ́sìn níwájú mi,ta l�� bẹ̀ yín ní gbogbo gìrìgìrì lásán, tí ẹ̀ ń dà ninu àgbàlá mi. +Ẹ má mú ẹbọ asán wá fún mi mọ́;ohun ìríra ni turari jẹ́ fún mi.Àjọ̀dún ìbẹ̀rẹ̀ oṣù titun, ọjọ́ ìsinmi, ati pípe àpéjọ.Ara mi kò gba ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dàpọ̀ mọ́ ẹ̀sìn mọ́. +Ninu ọkàn mi, mo kórìíra àwọn àjọ̀dún oṣù tuntun yín, ati àwọn àjọ̀dún pataki yín.Wọ́n ti di ẹrù wúwo fún mi,n kò lè gbé e mọ́, ó sú mi. +“Bí ẹ bá tẹ́wọ́ adura,n óo gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ yín.Ẹ̀ báà tilẹ̀ gbadura, gbaduran kò ní gbọ́;nítorí ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀, +Ẹ wẹ̀, kí ara yín dá ṣáká.Ẹ má hùwà burúkú níwájú mi mọ́.Ẹ má ṣe iṣẹ́ ibi mọ́. +Ẹ lọ kọ́ bí eniyan tí ń ṣe rere.Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́.Ẹ máa ran ẹni tí ara ń ni lọ́wọ́.Ẹ máa gbìjà aláìníbaba, kí ẹ sì máa gba ẹjọ́ opó rò.” +OLUWA ní, “Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí á jọ sọ àsọyé pọ̀.Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ pọ́n bí iná,yóo di funfun bí ẹfun.Bí ó tilẹ̀ pupa bí aṣọ àlàárì,yóo di funfun bí irun ọmọ aguntan funfun. +Bí ẹ bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́ràn,ẹ óo jẹ ire ilẹ̀ náà. +Máa gbọ́, ìwọ ọ̀run,sì fetí sílẹ̀, ìwọ ayéNítorí pé OLUWA ń sọ̀rọ̀Ó ní, “Lẹ́yìn tí mo bọ́ àwọn ọmọ,tí mo tọ́ wọn dàgbà tán,ọ̀tẹ̀ ni wọ́n dì sí mi. +Ṣugbọn tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ sì ṣoríkunkun;idà ni yóo run yín.”Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ. +Ìlú tí ó ti jẹ́ olódodo rí tí ń ṣe bí aṣẹ́wó,ìlú tí ó ti kún fún ẹ̀tọ́ ati òdodo rí, ti kún fún ìpànìyàn. +Fadaka rẹ ti di ìdàrọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.Wọ́n ti fi omi lú ọtí waini rẹ. +Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn ìjòyè rẹ, ati ẹgbẹ́ olè;gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí wọn sì ń wá ẹ̀bùn káàkiri.Wọn kì í gbèjà aláìníbaba,bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gba ẹjọ́ opó rò. +Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Alágbára Israẹli ní:“N óo bínú sí àwọn ọ̀tá mi,n óo sì gbẹ̀san lára àwọn tí ó kórìíra mi. +Nígbà tí mo bá gbá ọ mú,n óo finá jó gbogbo àìdára rẹ dànù.N óo sì mú gbogbo ìbàjẹ́ rẹ kúrò. +N óo dá àwọn onídàájọ́ rẹ pada sí ipò tí wọn ti wà tẹ́lẹ̀.Ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ,lẹ́yìn náà a óo máa pè ọ́ ní ìlú olódodo.” +A óo fi ẹ̀tọ́ ra Sioni pada;a óo sì fi òdodo ra àwọn tí ó bá ronupiwada ninu rẹ pada. +Ṣugbọn a óo pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ run,àwọn tí ó kọ OLUWA sílẹ̀ yóo sì ṣègbé. +Ojú yóo tì yín, fún àwọn igi Oaku tí ẹ nífẹ̀ẹ́ láti máa bọ.Ojú yóo sì tì yín fún àwọn ọgbà oriṣa tí ẹ yàn. +Mààlúù mọ olówó rẹ̀;kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sí mọ ibùjẹ tí oluwa rẹ̀ ṣe fún un;ṣugbọn Israẹli kò mọ nǹkan,òye kò yé àwọn eniyan mi.” +Nítorí pé ẹ óo dàbí igi oaku tí ó wọ́wé,ati bí ọgbà tí kò lómi. +Alágbára yóo dàbí ògùṣọ̀,iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ bí ìṣáná.Àwọn mejeeji ni yóo jóná pọ̀,kò sì ní sí ẹni tí yóo lè pa iná náà. +Háà! Orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀,àwọn eniyan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lọ,ìran oníṣẹ́ ibi;àwọn ọmọ tí ó kún fún ìwà ìbàjẹ́!Wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀,wọn kò náání Ẹni Mímọ́ Israẹliwọ́n sì ti kẹ̀yìn sí i. +Ṣé ẹ fẹ́ kí á tún jẹ yín níyà sí i ni,àbí kí ló dé tí ẹ kò fi jáwọ́ ninu ìwà ọ̀tẹ̀ tí ẹ̀ ń hù?Gbogbo orí yín jẹ́ kìkìdá egbò,gbogbo ọkàn yín sì rẹ̀wẹ̀sì. +Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí yín,kò síbìkan tí ó gbádùn.Gbogbo ara yín kún fún ọgbẹ́ ati egbò tí ń ṣẹ̀jẹ̀.Ẹnikẹ́ni kò wẹ egbò yín, wọn kò dì wọ́n,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi òògùn sí wọn. +Orílẹ̀-èdè yín ti di ahoro,wọ́n ti dáná sun àwọn ìlú yín.Àwọn àjèjì sì ti jẹ ilẹ̀ yín run níṣojú yín.Ó di ahoro bí èyí tí àwọn àjèjì wó palẹ̀. +Ó wá ku Jerusalẹmu bí àtíbàbà ninu ọgbà àjàrà,ati bí ahéré ninu oko ẹ̀gúsí;ó wá dàbí ìlú tí ogun dótì. +Bí kò bá ṣe pé OLUWA àwọn ọmọ ogun dá díẹ̀ sí ninu wa ni,à bá rí bí i Sodomu,à bá sì dàbí Gomora. +Asiria ṣe Àṣejù. +Àwọn tí ń ṣe òfin tí kò tọ́ gbé!Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn akọ̀wé, tí ń kọ̀wé láti ni eniyan lára; +Bí ọwọ́ mi ṣe tẹ àwọn ìlú àwọn abọ̀rìṣà,tí oriṣa wọn lágbára ju ti Jerusalẹmu ati Samaria lọ, +ṣé n kò ní lè ṣe sí Jerusalẹmu ati àwọn oriṣa rẹ̀bí mo ti ṣe Samaria ati àwọn oriṣa rẹ̀?” +Nígbà tí OLUWA bá parí bírà tí ó ń dá ní òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu,yóo fìyà jẹ ọba Asiria fún ìwà ìgbéraga ati àṣejù rẹ̀. +Nítorí ó ní,“Agbára mi ni mo fi ṣe èyí,ọgbọ́n mi ni mo fi ṣe énítorí pé mo jẹ́ amòye.Mo yí ààlà àwọn orílẹ̀-èdè pada,mo kó ẹrù tí ó wà ninu ilé ìṣúra wọn.Mo ré àwọn tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ bọ́ sílẹ̀ bí alágbára ọkunrin. +Mo nawọ́ kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,bí ẹni nawọ́ kó ọmọ ẹyẹ.Mo kó gbogbo ayé,bí ẹni kó ẹyin ẹyẹ tí ó kọ ẹyin rẹ̀ sílẹ̀, tí ó fò lọ,kò sí ẹnìkan tí ó lè ṣe nǹkankan,kò sí ẹnìkan tí ó lanu sọ̀rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbin.” +Ǹjẹ́ fáàrí àáké lè pọ̀ ju ti ẹni tí ó ń fi gégi lọ?Tabi ayùn lè fọ́nnu sí ẹni tí ó ń fi rẹ́ igi?Ǹjẹ́ kùmọ̀ lè mú ẹni tí ó ń lò ó lọ́wọ́,tabi kí ọ̀pá mú ẹni tí ó ni í lọ́wọ́? +Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo rán àìsàn apanirunsí ààrin àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀.Dípò ohun tí wọ́n fi ń ṣe ògo,ajónirun yóo jó wọn bí ìgbà tí iná bá jóni. +Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóo di iná,Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóo di ahọ́n iná;yóo sì jó àwọn ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn rẹ̀ run ní ọjọ́ kan. +OLUWA yóo pa àwọn igi ńlá inú igbó rẹ̀ run,yóo pa àwọn igi eléso ilẹ̀ rẹ́ tèsotèso,bí ìgbà tí àrùn bá gbẹ eniyan. +Ohun tí yóo kù ninu àwọn igi igbó rẹ̀kò ní ju ohun tí ọmọde lè kà, kí ó sì kọ sílẹ̀ lọ. +wọ́n ń dínà ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní,wọn kò sì jẹ́ kí àwọn talaka ààrin àwọn eniyan mi rí ẹ̀tọ́ wọn gbà,kí wọ́n lè sọ àwọn opó di ìkógun. +Ní ọjọ́ náà, ìyókù Israẹli ati àwọn tí yóo yè ní agbo ilé Jakọbu, kò ní gbé ara lé ẹni tí ó ṣá wọn lọ́gbẹ́ mọ́, ṣugbọn OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni wọn óo fẹ̀yìn tì ní òtítọ́. +Àwọn yòókù yóo pada, àwọn yòókù Jakọbu yóo pada sọ́dọ̀ Ọlọrun alágbára. +Israẹli, bí àwọn eniyan rẹ tilẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn etí òkun, díẹ̀ ninu wọn ni yóo pada, nítorí ìparun ti di òfin ó sì kún fún òdodo +Nítorí OLUWA, OLUWA, àwọn ọmọ ogun yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ní àṣeparí láàrin gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é lófin. +Nítorí náà OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi tí ń gbé Sioni, Ẹ má bẹ̀rù àwọn ará Asiria bí wọn bá fi ọ̀gọ lù yín, tabi tí wọn gbé ọ̀pá sókè si yín bí àwọn ará Ijipti ti ṣe si yín. +Nítorí pé láìpẹ́, ibinu mi si yín yóo kásẹ̀ nílẹ̀, n óo sì dojú ibinu mi kọ wọ́n láti pa wọ́n run. +Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, n óo fi ọ̀pá mi nà wọ́n, bí ìgbà tí mo na àwọn ará Midiani ní ibi àpáta Orebu. Ọ̀pá rẹ̀ yóo wà lórí òkun. Yóo tún gbé e sókè bí ó ti ṣe ní Ijipti. +Ní ọjọ́ náà, a óo gbé ẹrù tí ó dì lé ọ lórí kúrò, a óo sì fa àjàgà rẹ̀ dá kúrò lọ́rùn rẹ.” +Ó ti kúrò ní agbègbè Rimoni,ó ti dé sí Aiati;ó kọjá ní Migironi,ó kó ẹrù ogun rẹ̀ jọ sí Mikimaṣi. +Wọ́n sọdá sí òdìkejì odòwọ́n sùn ní Geba di ọjọ́ keji.Àwọn ará Rama ń wárìrì,àwọn ará Gibea, ìlú Saulu sá lọ. +Kí ni ẹ óo ṣe lọ́jọ́ ìjìyà yíntí ìparun bá dé láti òkèèrè?Ta ni ẹ óo sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́?Níbo ni ẹ óo kó ọrọ̀ yín sí? +Kígbe! Ìwọ ọmọbinrin Galimu.Fetí sílẹ̀ ìwọ Laiṣa,kí Anatoti sì dá a lóhùn. +Madimena ń sá lọ,àwọn ará Gebimu ń sá àsálà. +Ní òní olónìí, yóo dúró ní Nobu,yóo di ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn òkè Sioni,àní òkè Jerusalẹmu. +Ẹ wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun,yóo gé àwọn ẹ̀ka igi náà pẹlu agbára tí ó bani lẹ́rù.Yóo gé àwọn tí ó ga fíofío lulẹ̀,yóo sì rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀. +Yóo fi àáké gé àwọn igi igbó tí ó dí, Lẹbanoni pẹlu gbogbo igi ńláńlá rẹ̀ yóo sì wó. +Kò sí ohun tí ó kù àfi kí ẹ kú lójú ogun,tabi kí ẹ ká góńgó láàrin àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú.Sibẹsibẹ inú OLUWA kò ní rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró. +Háà! Asiria!Orílẹ̀-èdè tí mò ń lò bíi kùmọ̀, ati bíi ọ̀pánígbà tí inú bá bí mi. +Mo rán wọn láti gbógun ti àwọn tí kò mọ Ọlọrun,ati àwọn eniyan tí wọ́n bá mú mi bínú.Pé kí wọ́n kó wọn lẹ́rù.Kí wọ́n kó wọn lẹ́rúkí wọ́n tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi ẹrọ̀fọ̀tí à ń tẹ̀ mọ́lẹ̀ níta gbangba. +Ṣugbọn ọba Asiria kò pa irú ète yìí,kò sì ní irú èrò yìí lọ́kàn;gbogbo èrò ọkàn rẹ̀ ni láti pa ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè run +nítorí ó wí pé:“Ṣebí ọba ni gbogbo àwọn olórí ogun mi! +Ṣebí bíi Kakemiṣi ni Kalino rí,tí Hamati rí bíi Aripadi,tí Samaria kò sì yàtọ̀ sí Damasku? +Ìjọba Tí Ó Tòrò. +Èèhù kan yóo sọ jáde láti inú kùkùté igi Jese,ẹ̀ka kan yóo sì yọ jáde láti inú àwọn gbòǹgbò rẹ̀. +Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóo dúró bí àsíá fún àwọn orílẹ̀-èdè, òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa wá. Ibùgbé rẹ̀ yóo jẹ́ èyí tí ó lógo. +Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo na ọwọ́ rẹ̀ lẹẹkeji, yóo ra àwọn eniyan rẹ̀ yòókù pada ní oko ẹrú, láti Asiria, ati Ijipti, láti Patosi ati Etiopia, láti Elamu ati Ṣinari, láti Amati ati àwọn erékùṣù òkun. +Yóo gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,yóo kó àwọn Israẹli tí a ti patì jọ.Yóo ṣa àwọn ọmọ Juda tí wọ́n fọ́nká jọ,láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé. +Owú jíjẹ Efuraimu yóo kúrò,a óo sì pa àwọn tí ń ni Juda lára run.Efuraimu kò gbọdọ̀ jowú Juda mọ́,bẹ́ẹ̀ ni Juda kò gbọdọ̀ ni Efuraimu lára mọ. +Wọn óo kọlu àwọn ará Filistini ní ìhà ìwọ̀ oòrùn,wọn yóo jọ ṣẹgun àwọn ará ìlà oòrùn.Wọn yóo sì jọ dojú ìjà kọ Edomu ati Moabu.Àwọn ará Amoni yóo gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. +OLUWA yóo pa Ijipti run patapata. Yóo na ọwọ́ ìjì líle sí orí odò Pirati,yóo sì pín in sí ọ̀nà meje,kí àwọn eniyan lè máa ríbi là á kọjá. +Ọ̀nà tí ó gbòòrò yóo wà láti Asiria, fún ìyókù àwọn eniyan rẹ̀;bí ó ti ṣe wà fún àwọn ọmọ Israẹli,nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti. +Ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé e,ẹ̀mí ọgbọ́n ati òye,ẹ̀mí ìmọ̀ràn ati agbára,ẹ̀mí ìmọ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA. +Ìbẹ̀rù OLUWA ni yóo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀kì í ṣe ohun tí ó fojú rí,tabi èyí tí ó fi etí gbọ́ ni yóo fi ṣe ìdájọ́. +Ṣugbọn yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn talaka, yóo fi ẹ̀tọ́ gbèjà àwọn onírẹ̀lẹ̀,yóo fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ na ayé bíi pàṣán,yóo sì fi èémí ẹnu rẹ̀ pa àwọn oníṣẹ́ ibi. +Òdodo ni yóo fi ṣe àmùrè ìgbàdí rẹ̀, yóo sì fi òtítọ́ ṣe àmùrè ìgbànú rẹ̀. +Ìkookò yóo máa bá ọ̀dọ́ aguntan gbé,àmọ̀tẹ́kùn yóo sùn sílẹ̀ pẹlu ọmọ ewúrẹ́,ọmọ mààlúù, ati kinniun, ati ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa yóo jọ máa gbé pọ̀,ọmọ kékeré yóo sì máa kó wọn jẹ. +Mààlúù ati ẹranko beari yóo jọ máa jẹun pọ̀,àwọn ọmọ wọn yóo jọ máa sùn pọ̀,kinniun yóo sì máa jẹ koríko bí akọ mààlúù. +Ọmọ ọmú yóo máa ṣeré lórí ihò paramọ́lẹ̀,ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmúyóo máa fi ọwọ́ bọ inú ihò ejò. +Wọn kò ní ṣe eniyan ní jamba mọ́,tabi kí wọ́n bu eniyan jẹ ní gbogbo orí òkè mímọ́ mi. Nítorí ìmọ̀ OLUWA yóo kún gbogbo ayébí omi ṣe kún gbogbo inú òkun. +Orin Ọpẹ́. +O óo sọ ní ọjọ́ náà pé,“N óo fi ọpẹ́ fún OLUWA,nítorí pé bí ó tilẹ̀ bínú sí mi,inú rẹ̀ ti rọ̀, ó sì tù mí ninu. +Wò ó! Ọlọrun ni olùgbàlà mi, n óo gbẹ́kẹ̀lé eẹ̀rù kò sì ní bà mí,nítorí pé OLUWA Ọlọrun ni agbára mi, ati orin mi,òun sì ni Olùgbàlà mi.” +Tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa rí ìgbàlàbí ẹni pọn omi láti inú kànga. +Ẹ óo sọ ní ọjọ́ náà pé,“Ẹ fọpẹ́ fún OLUWA,ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,ẹ kéde iṣẹ́ rere rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;ẹ kéde pé a gbé orúkọ rẹ̀ ga. +Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWAnítorí ó ṣe nǹkan tí ó lógo,jẹ́ kí èyí di mímọ̀ ní gbogbo ayé. +Ẹ̀yin tí ń gbé Sioni,ẹ hó, ẹ kọrin ayọ̀, ẹ̀yin olùgbé Sioni,nítorí Ẹni ńlá ni Ẹni Mímọ́ Israẹlití ó wà láàrin yín.” +Ọlọrun Yóo Jẹ Babiloni Níyà. +Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Babiloni: +Nítorí àgbájọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóo kọ̀, wọn kò ní tan ìmọ́lẹ̀.Oòrùn yóo ṣókùnkùn nígbà tí ó bá yọ,òṣùpá kò sì ní tan ìmọ́lẹ̀. +N óo fìyà jẹ ayé nítorí iṣẹ́ ibi rẹ̀,n óo sì jẹ àwọn ìkà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.N óo fòpin sí àṣejù àwọn onigbeeraga,n óo rẹ ìgbéraga àwọn tí kò lójú àánú sílẹ̀. +N óo sọ eniyan di ohun tí ó ṣọ̀wọ́n ju wúrà dáradára lọ,irú eniyan yóo ṣọ̀wọ́n ju wúrà ilẹ̀ Ofiri lọ. +Nítorí náà n óo mú kí àwọn ọ̀run wárìrìayé yóo sì mì tìtì tóbẹ́ẹ̀ tí yóo sún kúrò ní ipò rẹ̀,nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ọjọ́ tí inú rẹ̀ bá ru. +Eniyan yóo dàbí àgbọ̀nrín tí ọdẹ ń lé,ati bí aguntan tí kò ní olùṣọ́;olukuluku yóo doríkọ ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀,wọn óo sì sá lọ sí ilẹ̀ wọn. +Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí, wọn óo fi ọ̀kọ̀ gún un pa,ẹni tí ọwọ́ bá tẹ̀, idà ni wọ́n ó fi pa á. +A óo so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ lójú wọn,a óo kó ilé wọn,a óo sì bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀ pẹlu agbára. +Wò ó! N óo rú àwọn ará Media sókè sí wọn,àwọn tí wọn kò bìkítà fún fadakabẹ́ẹ̀ ni wọn kò ka wúrà sí.Wọn óo wá bá Babiloni jà. +Wọn yóo fi ọfà pa àwọn ọdọmọkunrin,wọn kò ní ṣàánú oyún inú,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣàánú àwọn ọmọde. +Babiloni, ìwọ tí o lógo jù láàrin gbogbo ìjọba ayé, ìwọ tí o jẹ́ ẹwà ati ògo àwọn ará Kalidea,yóo dàbí Sodomu ati Gomora,nígbà tí Ọlọrun pa wọ́n run. +Ẹ ta àsíá ní orí òkè gíga,ẹ gbóhùn sókè sí wọn.Ẹ juwọ́, kí àwọn ológun gba ẹnu ibodè àwọn ọlọ́lá wọlé. +Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ láti ìran dé ìran,àwọn ará Arabia kankan kò ní pa àgọ́ sibẹ,bẹ́ẹ̀ ni àwọn darandaran kankan kò ní jẹ́ kí agbo aguntan wọn sinmi níbẹ̀. +Ṣugbọn àwọn ẹranko ní yóo máa sùn níbẹ̀ ilé rẹ̀ yóo sì kún fún ẹyẹ òwìwí,ògòǹgò yóo máa gbè ibẹ̀ẹhànnà òbúkọ yóo sì máa ta pọ́núnpọ́nún káàkiri ibẹ̀. +Àwọn ìkookò yóo máa ké ninu ilé ìṣọ́ rẹ̀, ààfin rẹ̀ yóo di ibùgbé àwọn ajáko,àkókò rẹ̀ súnmọ́ etílé,ọjọ́ rẹ̀ kò sì ní pẹ́ mọ́. +Èmi pàápàá ti pàṣẹ fún àwọn tí mo yà sọ́tọ̀,mo ti pe àwọn akọni mi, tí mo fi ń yangàn,láti fi ibinu mi hàn. +Gbọ́ ariwo lórí òkè, bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan,gbọ́ ariwo ìdàrúdàpọ̀ ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ń péjọ pọ̀!OLUWA àwọn ọmọ ogunní ń kó àwọn ọmọ ogun jọ fún ogun. +Wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè,láti ìpẹ̀kun ayé.OLUWA ń bọ̀ pẹlu àwọn ohun ìjà ibinu rẹ̀,tí yóo fi pa gbogbo ayé run. +Ẹ pohùnréré ẹkún, nítorí pé ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé,yóo dé bí ìparun láti ọwọ́ Olodumare. +Nítorí náà ọwọ́ gbogbo eniyan yóo rọ,ọkàn gbogbo eniyan yóo rẹ̀wẹ̀sì; +ẹnu yóo sì yà wọ́n.Ìpayà ati ìrora yóo mú wọn,wọn yóo wà ninu ìrora bí obinrin tí ó ń rọbí;wọn óo wo ara wọn tìyanu-tìyanu,ojú yóo sì tì wọ́n. +Wò ó! Ọjọ́ OLUWA dé tán,tìkàtìkà pẹlu ìrúnú ati ibinu gbígbóná láti sọ ayé di ahoro,ati láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run. +Ìpadàbọ̀ láti Ìgbèkùn. +OLUWA yóo ṣíjú àánú wo Jakọbu yóo tún yan Israẹli, yóo sì fi wọ́n sórí ilẹ̀ wọn. Àwọn àlejò yóo darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóo sì di ọ̀kan náà pẹlu ilé Jakọbu. +Gbogbo wọn yóo wí fún ọ pé,‘Àárẹ̀ ti mu yín gẹ́gẹ́ bí ó ti mú àwa náà.Ẹ ti dàbí i wa. +A ti fa ògo yín ati ohùn hapu yín sinu isà òkú.Ìdin di ibùsùn tí ẹ sùn lé lóríàwọn kòkòrò ni ẹ sì fi bora bí aṣọ.’ +“Ọba Babiloni, wò ó! Bí o ti jábọ́ láti ojú ọ̀run, ìwọ tí o dàbí ìràwọ̀ òwúrọ̀!Wò ó bí a ti sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀,ìwọ tí o ti pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè run rí. +Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé,‘N óo gòkè dé ọ̀run,n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run;n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan,ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré. +N óo gòkè kọjá ìkùukùu ojú ọ̀run,n óo wá dàbí Olodumare.’ +Ṣugbọn a já ọ lulẹ̀ sinu isà òkú, sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun. +“Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ọ yóo tẹjú mọ́ ọ,wọ́n óo fi ọ́ ṣe àríkọ́gbọ́n pé,‘Ṣé ọkunrin tí ó ń kó ìpayà bá gbogbo ayé nìyí,tí ó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì; +ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀,tí ó sì pa àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ run,ẹni tí kì í dá àwọn tí ó bá wà ní ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀?’ +Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dùbúlẹ̀ ninu ògo wọnolukuluku ninu ibojì tirẹ̀. +Ṣugbọn a lé ìwọ kúrò ninu ibojì rẹ,bí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé,tí a gbé òkú rẹ̀ sọnù;tí a jù sáàrin òkú àwọn jagunjagun tí a pa lójú ogun;àwọn tí a jù sinu kòtò olókùúta,bí àwọn tí a tẹ̀ ní àtẹ̀pa. +Àwọn orílẹ̀-èdè yóo ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pada sí ilẹ̀ wọn, àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì di ẹrú fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọn yóo pada sọ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú di ẹrú, wọn yóo sì jọba lórí àwọn tí ó ni wọ́n lára. +A kò ní sin ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba yòókù,nítorí pé o ti pa ilẹ̀ rẹ run,o sì ti pa àwọn eniyan rẹ.Kí á má dárúkọ àwọn ìran ẹni ibi mọ́ títí lae! +Ẹ múra láti pa àwọn ọmọ rẹ̀ runnítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn,kí wọn má baà tún gbógun dìde,kí wọn gba gbogbo ayé kan,kí wọn sì kọ́ ọpọlọpọ ìlú sórí ilẹ̀ ayé.” +OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo gbógun tì wọ́n, n óo pa orúkọ Babiloni rẹ́ ati ìyókù àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ̀, ati arọmọdọmọ wọn. +N óo sọ ọ́ di ibùgbé òòrẹ̀, adágún omi yóo wà káàkiri inú rẹ, n óo sì fi ọwọ̀ ìparun gbá a. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA àwọn ọmọ ogun ti búra, ó ní,“Bí mo ti rò ó bẹ́ẹ̀ ni yóo rí;ohun tí mo pinnu ni yóo sì ṣẹ. +Pé n óo pa àwọn ará Asiria run lórí ilẹ̀ mi;n óo sì fẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè mi.Àjàgà rẹ̀ yóo bọ́ kúrò lọ́rùn àwọn eniyan mi,ati ẹrù tí ó dì lé wọn lórí. +Ohun tí mo ti pinnu nípa gbogbo ayé nìyí,mo sì ti na ọwọ́ mi sórí orílẹ̀-èdè gbogbo láti jẹ wọ́n níyà.” +OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu; ta ni ó lè yí ìpinnu rẹ̀ pada?Ó ti dáwọ́lé ohun tí ó fẹ́ ṣeta ni lè ká a lọ́wọ́ kò? +Ọ̀rọ̀ OLUWA tí Aisaya sọ ní ọdún tí ọba Ahasi kú: +Gbogbo ẹ̀yin ará Filistini,ẹ má yọ̀ pé a ti ṣẹ́ ọ̀pá tí ó lù yín;nítorí pé paramọ́lẹ̀ ni yóo yọ jáde láti inú àgékù ejò,ejò tí ń fò sì ni ọmọ rẹ̀ yóo yà. +Nígbà tí OLUWA bá fun yín ní ìsinmi kúrò ninu làálàá ati rògbòdìyàn ati iṣẹ́ àṣekára tí wọn ń fi tipá mu yín ṣe, +Àkọ́bí talaka yóo rí oúnjẹ jẹ,aláìní yóo sì dùbúlẹ̀ láì léwu.Ṣugbọn n óo fi ìyàn pa àwọn ọmọ ilẹ̀ rẹ,a óo sì fi idà pa àwọn tó kù ní ilẹ̀ rẹ. +Máa sọkún, ìwọ ẹnubodè, kí ìwọ ìlú sì figbe ta.Ẹ̀yin ará Filistini, ẹ máa gbọ̀n jìnnìjìnnìnítorí pé àwọn ọmọ ogun kan ń rọ́ bọ̀ bí èéfín, láti ìhà àríwá,kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun wọntí ó ń ṣe dìẹ̀dìẹ̀ bọ̀ lẹ́yìn. +Èsì wo ni a óo fún àwọn ikọ̀ orílẹ̀-èdè Filistini?A óo sọ fún wọn pé,“OLUWA ti fi ìdí Sioni sọlẹ̀àwọn tí à ń pọ́n lójú láàrin àwọn eniyan rẹ̀yóo fi ibẹ̀ ṣe ibi ààbò.” +ẹ óo kọrin òwe bú ọba Babiloni pé:“Agbára aninilára ti pinìpayà ojoojumọ ti dópin. +OLUWA ti ṣẹ́ ọ̀pá àṣẹ àwọn ẹni ibi,ati ọ̀pá àṣẹ àwọn olórí +tí wọn ń fi ibinu lu àwọn eniyan láì dáwọ́ dúró,tí wọn ń fi ibinu ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè,tí ó ń ṣe inúnibíni lemọ́lemọ́. +Gbogbo ayé wà ní ìsinmi ati alaafiawọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin ayọ̀. +Àwọn igi Sipirẹsi ń yọ̀ yín;àwọn igi Kedari ti Lẹbanoni sì ń sọ pé,‘Láti ìgbà tí a ti rẹ ọba Babiloni sílẹ̀,kò sí agégi kan tí ó wá dààmú wa mọ́.’ +“Isà òkú ti lanu sílẹ̀ láti pàdé rẹ bí o bá ti ń dé.Ó ta àwọn òkú ọ̀run jí láti kí ọ,àwọn tí wọ́n ṣe pataki ní àkókò wọn,Ó gbé gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn. +OLUWA yóo Pa Moabu Run. +Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ nípa ilẹ̀ Moabu nìyí: Nítorí tí a wó ìlú Ari ati Kiri lulẹ̀ ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo,ó parí fún Moabu. +Àwọn ọmọbinrin Diboni ti gun àwọn ibi pẹpẹ tí wọ́n ti ń bọ̀rìṣà lọ, wọ́n lọ sọkún.Moabu ń pohùnréré ẹkún nítorí Nebo ati Medeba.Gbogbo orí wọn pá, wọ́n sì ti fá gbogbo irùngbọ̀n wọn. +Wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora ní ìta gbangba.Gbogbo wọn dúró lórí òrùlé ilé wọn,ati ní gbogbo gbàgede, wọ́n ń pohùnréré ẹkún,omijé sì ń dà lójú wọn. +Heṣiboni ati Eleale ń kígbe lóhùn rara,àwọn ará Jahasi gbọ́ ariwo wọn;nítorí náà àwọn ọmọ ogun Moabu sọkún,ọkàn rẹ̀ sì wárìrì. +Ọkàn mi sọkún fún Moabu;àwọn ìsáǹsá rẹ̀ sá lọ sí Soari ati Egilati Ṣeliṣiya.Ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Luhiti, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ,wọ́n sì ń kígbe arò bí wọ́n tí ń lọ sí Horonaimu. +Àwọn odò Nimrimu di aṣálẹ̀,koríko ibẹ̀ gbẹ;àwọn ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ jóná mọ́lẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ewé kò rú mọ́. +Nítorí náà àwọn ohun tí wọ́n ní lọpọlọpọati ohun ìní tí wọn ti kó jọ,ni wọ́n kó lọ sí ìkọjá odò Wilo. +Nítorí ariwo kan ti gba gbogbo ilẹ̀ Moabu kan,ẹkún náà dé Egilaimu,ìpohùnréré náà sì dé Beerelimu. +Nítorí odò Diboni kún fún ẹ̀jẹ̀,sibẹsibẹ n óo jẹ́ kí ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ dé bá a.Kinniun ni yóo pa àwọn ará Moabu tí ó bá ń sá lọati àwọn eniyan tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà. +Kò sí Ìrètí fún Moabu Mọ́. +Wọ́n ti kó àgbò láti Sela, ní ọ̀nà aṣálẹ̀,wọ́n fi ranṣẹ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, ní òkè Sioni. +Wọ́n ti kó ayọ̀ ati ìdùnnú lọ kúrò ninu oko eléso;ẹnikẹ́ni kò kọrin bẹ́ẹ̀ ni kò sí ariwo híhó ninu ọgbà àjàrà wọn.Kò sí àwọn tí ó ń pọn ọtí ninu rẹ̀ mọ́bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ariwo àwọn tí ń pọn ọtí mọ́. +Nítorí náà, ẹ̀mí mi kọrin arò bíi ti dùùrù fún Moabu,ọkàn mi kérora, fún Moabu ati Kiri Heresi. +Nígbà tí Moabu bá wá siwaju,tí ó fi gbogbo agbára gbadura ninu ilé oriṣa rẹ̀,títí ó fi rẹ̀ ẹ́,adura rẹ̀ kò ní gbà. +Ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti kọ́ sọ nípa Moabu tẹ́lẹ̀ nìyí. +Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA ní, “Nígbà tí a óo fi rí ọdún mẹta, tíí ṣe iye ọdún alágbàṣe, a óo ti sọ ògo Moabu di ilẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan inú rẹ̀ pọ̀, àwọn d��ẹ̀ ni yóo ṣẹ́kù, àárẹ̀ yóo sì ti mú wọn.” +Àwọn ọmọbinrin Moabu dúró létí odò Anoni,wọ́n ń rìn síwá, sẹ́yìn,wọ́n ń lọ sókè, sódò,bí ọmọ ẹyẹ tí a lé kúrò ninu ìtẹ́. +“Gbà wá ní ìmọ̀ràn,máa ṣe ẹ̀tọ́ fún wa.Fi òjìji rẹ dáàbò bò wá,kí ara lè tù wá lọ́sàn-án gangan,bí ẹni pé alẹ́ ni.Dáàbò bo àwọn tí a lé jáde;má tú àṣírí ẹni tí ń sálọ. +Jẹ́ kí àwọn tí a lé jáde ní Moabu, máa gbé ààrin yín.Dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn apanirun.”Nígbà tí aninilára kò bá sí mọ́ tí ìparun bá dópin,tí atẹnimọ́lẹ̀ bá ti kúrò ní ilẹ̀ náà. +Nígbà náà a óo fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ pẹlu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.Ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo yóo jókòó lórí ìtẹ́ náà,Yóo dúró lórí òtítọ́ ní ìdílé Dafidi. +A ti gbọ́ ìròyìn ìgbéraga Moabu,bí ó ṣe ń ṣe àfojúdi tí ó sì ń sọ ìsọkúsọ:ṣugbọn lásán ni ìgbéraga rẹ̀. +Nítorí náà, kí Moabu máa pohùnréré ẹkún,kí gbogbo eniyan máa sun ẹkún arò ní Moabu.Wọn óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,nígbà tí wọn ba ranti àkàrà Kiri Heresi,tí ó ní èso àjàrà ninu. +Gbogbo oko ni ó rọ ní Heṣiboni;bẹ́ẹ̀ náà ni ọgbà Sibuma:àwọn olórí orílẹ̀-èdè ti gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lulẹ̀,èyí tí ó tàn kálẹ̀ dé Jaseri títí dé inú aṣálẹ̀.Ìtàkùn rẹ̀ tàn kálẹ̀,wọ́n kọjá sí òdìkejì òkun. +Nítorí náà mo sọkún fún ọgbà àjàrà Sibumabí mo ṣe sọkún fún Jaseri;mo sì sọkún nítorí Heṣiboni ati Eleale,mo sọkún, omi ń dà lójú mi pòròpòrònítorí gbogbo ìkórè yín, ati èso oko yín ni ogun ti kó lọ. +Ọlọrun Yóo Jẹ Siria ati Israẹli Níyà. +Ọ̀rọ̀ OLUWA sí ilẹ̀ Damasku nìyí: “Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́òkítì àlàpà ni yóo dà. +Nítorí pé ẹ ti gbàgbé Ọlọrun olùgbàlà yín,ẹ kò ranti Àpáta tí ó jẹ́ ààbò yín.Nítorí náà bí ẹ tilẹ̀ gbin igi dáradára tí ẹ̀ ń bọ ọ́,tí ẹ sì gbin òdòdó àjèjì tí ẹ̀ ń sìn ín; +wọn ìbáà hù lọ́jọ́ tí ẹ gbìn wọ́n,kí wọ́n yọ òdòdó ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí ẹ lọ́ wọnsibẹsibẹ kò ní sí ìkórèní ọjọ́ ìbànújẹ́ ati ìrora tí kò lóògùn. +Ẹ gbọ́ ariwo ọ̀pọ̀ eniyan,wọ́n ń hó bí ìgbì òkun.Ẹ gbọ́ ìró àwọn orílẹ̀-èdèwọ́n ń hó bíi ríru omi òkun ńlá. +Ìró àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ti omi òkun ńláṣugbọn OLUWA yóo bá wọn wí wọn óo sì sá lọ.Wọn óo dàbí ìràwé tí afẹ́fẹ́ ń gbé lọ lórí òkè,ati bí eruku tí ìjì líle ń fẹ́ kiri. +Ìdágìrì yóo bá wọn ní ìrọ̀lẹ́,kí ilẹ̀ tó mọ́ wọn kò ní sí mọ́;bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn tí wọ́n fogun kó wa,bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù lọ. +Àwọn ìlú rẹ̀ yóo di àkọ̀tì títí laewọn yóo di ibùjẹ àwọn ẹran,níbi tí àwọn ẹran yóo dùbúlẹ̀,tí ẹnikẹ́ni kò sì ní dẹ́rùbà wọ́n. +Ìlú olódi kò ní sí mọ́ ní Efuraimu,kò sì ní sí ìjọba mọ́ ní Damasku,àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Siriayóo sì dàbí ògo àwọn ọmọ Israẹli,OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀. +“Tó bá di ìgbà náà,a óo rẹ ògo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀,ọrọ̀ wọn yóo di àìní. +Yóo dàbí ìgbà tí eniyan kórè ọkà lóko,tí ó kó ṣiiri ọkà kún apá.Tí àwọn kan tún wá ṣa ọkà yòókù,tí àwọn tí wọn kọ́ kórè ọkà gbàgbé ní àfonífojì Refaimu. +Àṣàkù yóo kù níbẹ̀,bí ìgbà tí eniyan gbọn igi olifi,yóo ku meji tabi mẹta péré ní góńgó orí igi,tabi bíi mẹrin tabi marun-un lórí ẹ̀ka igi.”OLUWA Ọlọrun Israẹli ló sọ bẹ́ẹ̀. +Tó bá di ìgbà náà, àwọn eniyan yóo bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wọn, wọn yóo sì máa wo ojú Ẹni Mímọ́ Israẹli. +Wọn kò ní náání pẹpẹ tí wọ́n fọwọ́ ara wọn tẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gbójúlé àwọn ère tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe, ìbáà jẹ́ oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari. +Tó bá di ìgbà náà, àwọn ìlú olódi ńláńlá wọn yóo dàbí àwọn ìlú tí àwọn ará Hifi ati àwọn ará Amori sá kúrò níbẹ̀, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbógun tì wọ́n; gbogbo rẹ̀ yóo di ahoro. +Ọlọrun yóo Jẹ Sudani Níyà. +Ó ṣe, ní òkè àwọn odò kan ní ilẹ̀ Sudaniibìkan wà tí àwọn ẹyẹ ti ń fò pẹ̀ẹ̀rẹ̀pẹ̀. +Ẹni tí ó rán ikọ̀ lọ sí òkè odò Naili,tí wọ́n fẹní ṣọkọ̀ ojú omi.Ẹ lọ kíá, ẹ̀yin iranṣẹ ayára-bí-àṣá,ẹ lọ sọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tí ara wọn ń dán,àwọn tí àwọn eniyan tí wọ́n súnmọ́ wọnati àwọn tí ó jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù.Orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sìí máa ń ṣẹgun ọ̀tá,àwọn tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá. +Gbogbo aráyé,ẹ̀yin tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé,nígbà tí a bá gbé àsíá sókè lórí àwọn òkè,ẹ wò ó, nígbà tí a bá fun fèrè ogun, ẹ gbọ́. +Nítorí pé OLUWA sọ fún mi péòun óo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wolẹ̀ láti ibi ibùgbé òunbí ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán gangan,ati bí ìkùukùu ninu ooru ìgbà ìkórè. +Nítorí pé kí ó tó di ìgbà ìkórè,lẹ́yìn tí ìtànná àjàrà bá ti rẹ̀, tí ó di èso,tí àjàrà bẹ̀rẹ̀ sí gbó, tí ó ń pọ́n bọ̀,ọ̀tá yóo ti dòjé bọ àwọn ìtàkùn àjàrà,yóo sì gé gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ kúrò. +Gbogbo wọn yóo wà nílẹ̀,wọn yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ orí òkè,ati àwọn ẹranko inú ìgbẹ́.Àwọn ẹyẹ yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,àwọn ẹranko yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ jẹ ní ìgbà òtútù. +Ní àkókò náà, àwọn eniyan tí wọ́n ga, tí wọ́n sì ń dán,tí àwọn tí wọ́n súnmọ́ wọn, ati àwọn tí wọ́n jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù,orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sì í máa ń ṣẹgun ọ̀tá,tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá,wọn óo mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA àwọn ọmọ ogun,ní orí òkè Sioni, tí àwọn eniyan ń jọ́sìn ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun. +Ọlọrun Yóo Jẹ Ijipti Níyà. +Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ijipti nìyí:OLUWA gun ìkùukùu lẹ́ṣin, ó ń yára bọ̀ wá sí Ijipti.Àwọn oriṣa Ijipti yóo máa gbọ̀n níwájú rẹ̀,ọkàn àwọn ará Ijipti yóo sì dàrú. +Àwọn eniyan pataki ilẹ̀ náà yóo di ẹni ilẹ̀,ìbànújẹ́ yóo sì bá àwọn alágbàṣe. +Òmùgọ̀ ni àwọn olórí wọn ní Soani;ìmọ̀ràn wèrè sì ni àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ìgbìmọ̀ Farao ń fún eniyan.Báwo ni eniyan ṣe lè sọ fún Farao pé,“Ọmọ Ọlọ́gbọ́n eniyan ni mí,ọmọ àwọn ọba àtijọ́.” +Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n rẹ dà?Níbo ni wọ́n wà kí wọ́n sọ fún ọ,kí wọ́n sì fi ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti ṣe sí Ijipti hàn ọ́. +Àwọn olórí wọn ní Soani ti di òmùgọ̀,àwọn olórí wọn ní Memfisi sì ti gba ẹ̀tàn;àwọn tí wọ́n jẹ́ òpómúléró ní ilẹ̀ Ijipti ti ṣi Ijipti lọ́nà. +OLUWA ti dá èdè-àìyedè sílẹ̀ láàrin wọn,wọ́n sì ti ṣi Ijipti lọ́nà ninu gbogbo ìṣe rẹ̀,bí ìgbà tí ọ̀mùtí bá ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n ninu èébì rẹ̀. +Kò sí nǹkankan tí ẹnìkan lè ṣe fún Ijipti,kì báà jẹ́ ọlọ́lá tabi mẹ̀kúnnù,kì báà jẹ́ eniyan pataki tabi ẹni tí kò jẹ́ nǹkan. +Tí ó bá di ìgbà náà, àwọn ará Ijipti yóo di obinrin. Wọn yóo máa gbọ̀n, fún ẹ̀rù, nígbà tí OLUWA àwọn ọmọ ogun bá gbá wọn mú. +Ilẹ̀ Juda yóo di ẹ̀rù fún àwọn ará Ijipti, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóo bẹ̀rù nítorí ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu láti ṣe sí Ijipti. +Tó bá di ìgbà náà, ìlú marun-un yóo wà ní ilẹ̀ Ijipti, tí wọn yóo máa sọ èdè Kenaani; wọ́n óo búra láti jẹ́ ti OLUWA àwọn ọmọ ogun.Orúkọ ọ̀kan ninu wọn yóo máa jẹ́ ìlú Oòrùn. +Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA láàrin ilẹ̀ Ijipti, ọ̀wọ̀n OLUWA kan yóo sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ààlà ilẹ̀ rẹ̀. +N óo dá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Ijipti,olukuluku yóo máa bá arakunrin rẹ̀ jà,àwọn aládùúgbò yóo máa bá ara wọn jà,ìlú kan yóo gbógun ti ìlú keji,ìjọba yóo máa dìde sí ara wọn. +Yóo jẹ́ àmì ati ẹ̀rí fún OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe OLUWA nítorí àwọn aninilára, OLUWA yóo rán olùgbàlà tí yóo gbà wọ́n sí wọn. +OLUWA yóo sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Ijipti, wọn óo sì mọ OLUWA nígbà náà. Wọ́n yóo máa sin OLUWA pẹlu ẹbọ ati ẹbọ sísun; wọn óo jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, wọn yóo sì mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ. +OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ará Ijipti ṣugbọn yóo wò wọ́n sàn, wọn yóo pada sọ́dọ̀ OLUWA, yóo gbọ́ adura wọn, yóo sì wò wọ́n sàn. +Tó bá di ìgbà náà, ọ̀nà tí ó tóbi kan yóo wà láti Ijipti dé Asiria–àwọn ará Asiria yóo máa lọ sí Ijipti, àwọn ará Ijipti yóo sì máa lọ sí Asiria; àwọn ará Ijipti yóo máa jọ́sìn pẹlu àwọn ará Asiria. +Ní àkókò náà, Israẹli yóo ṣìkẹta Ijipti ati Asiria, wọn yóo sì jẹ́ ibukun lórí ilẹ̀ fún àwọn ará Ijipti, àwọn eniyan mi. +Tí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti súre fún pé, “Ibukun ni fún Ijipti, àwọn eniyan mi, ati fún Asiria tí mo fi ọwọ́ mi dá, ati fún Israẹli ìní mi.” +Ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá àwọn ará Ijipti,n óo sọ ète wọn di òfo.Wọn yóo lọ máa wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn oriṣa ati àwọn aláfọ̀ṣẹati lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, ati àwọn oṣó. +Ṣugbọn n óo fi Ijipti lé aláìláàánú akóniṣiṣẹ́ kan lọ́wọ́ìkà kan ni yóo sì jọba lé wọn lórí,bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, OLUWA àwọn ọmọ ogun wí. +Omi odò Naili yóo gbẹ,yóo gbẹ, àgbẹkanlẹ̀. +Gbogbo odò wọn yóo máa rùn,gbogbo àwọn odò tí ó ṣàn wọ odò Naili ní Ijipti,ni yóo fà, tí yóo sì gbẹ:Gbogbo koríko odò yóo rà. +Etí odò Naili yóo di aṣálẹ̀,gbogbo ohun tí wọ́n bá gbìn sibẹ yóo gbẹ,ẹ̀fúùfù óo sì gbá wọn dànù. +Àwọn apẹja tí ń fi ìwọ̀ ninu odò Nailiyóo ṣọ̀fọ̀,wọn óo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn;àwọn tí ń fi àwọ̀n pẹja yóo kérora. +Ìdààmú yóo bá àwọn tí ó ń hun aṣọ funfun,ati àwọn ahunṣọ tí ń lo òwú funfun. +Alaafia Ayérayé. +Ọ̀rọ̀ tí Aisaya ọmọ Amosi sọ nípa Juda ati Jerusalẹmu nìyí: +Ẹ wọnú àpáta lọ, kí ẹ sì farapamọ́ sinu ilẹ̀.Ẹ sá fún ibinu OLUWAati ògo ọlá ńlá rẹ̀. +A óo rẹ ọlọ́kàn gíga eniyan sílẹ̀,a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀;OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà. +Nítorí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀,tí yóo dojú ìjà kọ àwọn agbéraga,ati àwọn ọlọ́kàn gíga,ati gbogbo nǹkan tí à ń gbéga. +Yóo dojú kọ gbogbo igi Kedari ti Lẹbanoni,tí ó ga fíofío, ati gbogbo igi oaku ilẹ̀ Baṣani; +ati gbogbo àwọn òkè ńláńlá,ati gbogbo òkè gíga, +ati gbogbo ilé-ìṣọ́ gígaati gbogbo odi tí ó lágbára, +ati gbogbo ọkọ̀ ojú omi láti ìlú Taṣiṣi,ati gbogbo ọkọ̀ tí ó dára. +Àwọn ọlọ́kàn gíga yóo di ẹni ilẹ̀,a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀.OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà, +àwọn oriṣa yóo sì pòórá patapata. +Àwọn eniyan yóo sá sinu ihò àpáta,wọn yóo sì wọ inú ihò ilẹ̀ lọ,nígbà tí wọ́n bá ń sá fún ibinu OLUWA,ati ògo ọlá ńlá rẹ̀nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì. +Ní ọjọ́ iwájúòkè ilé OLUWA yóo fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òkè tí ó ga jùlọ,a óo sì gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ.Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo wá sibẹ. +Ní ọjọ́ náà,àwọn eniyan óo kó àwọn ère fadaka wọn dànù,ati àwọn ère wúrà tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe, tí wọn tún ń bọ.Wọn yóo dà wọ́n fún àwọn èkúté ati àwọn àdán. +Wọn óo wọ inú pàlàpálá àpáta,ati inú ihò àwọn òkè gíga;nígbà tí wọn bá ń sá fún ibinu OLUWA,ati ògo ọlá ńlá rẹ̀,nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì. +Ẹ má gbẹ́kẹ̀lé eniyan mọ́.Ẹlẹ́mìí ni òun alára,nítorí pé kí ni ó lè ṣe? +Ọpọlọpọ eniyan ni yóo wá, tí wọn yóo máa wí pé:“Ẹ wá! Ẹ jẹ́ kí á gun òkè OLUWA lọ,kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu,kí ó lè kọ́ wa ní ìlànà rẹ̀,kí á sì lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.Nítorí pé láti Sioni ni òfin Ọlọrun yóo ti jáde wáọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì wá láti Jerusalẹmu.” +Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè; yóo sì bá ọpọlọpọ eniyan wí.Wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́,wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́. +Ẹ̀yin ìdílé Jakọbuẹ wá, ẹ jẹ́ kí á rìn ninu ìmọ́lẹ̀ OLUWA. +Nítorí o ti ta àwọn eniyan rẹ nù,àní, ìdílé Jakọbu.Nítorí pé àwọn aláfọ̀ṣẹ ará ìhà ìlà oòrùn pọ̀ láàrin wọn,àwọn alásọtẹ́lẹ̀ sì pọ̀ bíi ti àwọn ará Filistini,Wọ́n ti gba àṣà àwọn àjèjì. +Wúrà ati fadaka kún ilẹ̀ wọn,ìṣúra wọn kò sì lópin.Ẹṣin kún ilẹ̀ wọn,kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lóǹkà. +Ilẹ̀ wọn kún fún oriṣa,wọ́n ń bọ iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,wọ́n ń wólẹ̀ fún ohun tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe. +Bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe tẹ ara rẹ̀ lórí batí ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.Oluwa, máṣe dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. +Àmì Wolii tó Wà Níhòhò. +Ní ọdún tí Sagoni, ọba Asiria, rán olórí ogun rẹ̀ pé kí ó lọ bá ìlú Aṣidodu jagun, tí ó gbógun ti ìlú náà, tí ó sì gbà á, +OLUWA sọ fún Aisaya ọmọ Amosi pé, “Dìde, bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ tí o lọ́ mọ́ra, sì bọ́ bàtà tí o wọ̀ sí ẹsẹ̀.” Aisaya bá ṣe bí OLUWA ti wí: ó bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ lára, ó sì bọ́ bàtà kúrò lẹ́sẹ̀. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rìn kiri ní ìhòòhò, láìwọ bàtà. +Lẹ́yìn ọdún mẹta, OLUWA dáhùn pé, “Bí Aisaya, iranṣẹ mi, ti rìn ní ìhòòhò tí kò sì wọ bàtà fún ọdún mẹta yìí, jẹ́ àmì ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kuṣi: +Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria yóo ṣe kó àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Kuṣi lẹ́rú, ati ọmọde ati àgbàlagbà wọn, ní ìhòòhò, láì wọ bàtà. A óo bọ́ aṣọ kúrò lára wọn, kí ojú ó lè ti Ijipti. +Ìbẹ̀rù-bojo yóo dé ba yín, ojú yóo sì tì yín; nítorí Kuṣi ati Ijipti tí ẹ gbójú lé. +Àwọn tí ń gbé etí òkun ilẹ̀ yìí yóo wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ẹ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a gbójú lé, àwọn tí à ń sá tọ̀ lọ pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́, kí wọ́n gbà wá lọ́wọ́ ọba Asiria. Báwo ní àwa óo ṣe wá là báyìí?’ ” +Ìran nípa Ìṣubú Babiloni. +Àsọtẹ́lẹ̀ nípa aṣálẹ̀ etí òkun nìyí:àjálù kan ń já bọ̀ láti inú aṣálẹ̀,láti ilẹ̀ tí ó bani lẹ́rù,ó ń bọ̀ bí ìjì líle tí ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá aṣálẹ̀. +Ẹ̀yin eniyan mi tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀,bí ẹni tẹ ọkà ní ibi ìpakà,ohun tí mo gbọ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun,Ọlọrun Israẹli, ní mò ń kéde fun yín yìí. +Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Edomu nìyí:Ẹnìkan ń pè mí láti SeiriÓ ní: “Aṣọ́nà, Òru ti rí o?Aṣọ́nà, àní òru ti rí?” +Aṣọ́nà bá dáhùn, ó ní:“Ilẹ̀ ń ṣú, ilẹ̀ sì ń mọ́.Bí ẹ bá tún fẹ́ bèèrè,ẹ pada wá, kí ẹ tún wá bèèrè.” +Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Arabia nìyí:Ninu igbó Arabia ni ẹ óo sùn, ẹ̀yin èrò ará Didani. +Ẹ bu omi wá fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ.Ẹ gbé oúnjẹ pàdé ẹni tí ń sá fógun, ẹ̀yin ará ilẹ̀ Tema. +Wọ́n ń sá fún idà,wọ́n sá fún idà lójú ogun.Wọ́n ń sá fún àwọn tafàtafà,wọ́n sá fún líle ogun. +OLUWA sọ fún mi pé, “Kí ó tó tó ọdún kan, ní ìwọ̀n ọdún alágbàṣe kan, gbogbo ògo Kedari yóo dópin; +díẹ̀ ni yóo sì kù ninu àwọn tafàtafà alágbára ọmọ Kedari; nítorí OLUWA Ọlọrun Israẹli ló sọ bẹ́ẹ̀.” +Ìran tí a fi hàn mí yìí le:Àwọn oníjàgídíjàgan lọ digun kó ìkógun,abanǹkanjẹ́ sì ba nǹkan jẹ́.Ẹ̀yin ará Elamu, ẹ gòkè lọ!Ẹ̀yin ará Media, ẹ múra ogun!Mo ti fòpin sí òṣé ati ìjìyà tí Babiloni kó bá gbogbo eniyan. +Nítorí náà, gbogbo ẹ̀gbẹ́ ní ń dùn mí,gbogbo ara ní ń ro míbí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́.A tẹrí mi ba kí n má baà gbọ́ nǹkankan,wọ́n dẹ́rù bà mí kí n má baà ríran. +Ọkàn mi dààmú, jìnnìjìnnì dà bò mí;wọ́n ti sọ àfẹ̀mọ́júmọ́ tí mò ń retí di ìbẹ̀rù mọ́ mi lọ́wọ́. +Wọ́n tẹ́ tabili, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sílẹ̀wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu.Ariwo bá ta pé“Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin ológun!Ẹ fepo pa asà yín.” +Nítorí OLUWA wí fún mi pé:“Lọ fi aṣọ́nà ṣọ́ ojú ọ̀nà,kí ó máa kéde ohun tí ó bá rí. +Nígbà tí ó bá rí àwọn ẹlẹ́ṣintí wọn ń bọ̀ ní meji-meji, bí ó bá rí ití àwọn kan gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,tí àwọn kan gun ràkúnmí,kí ó fara balẹ̀ dáradára,kí ó dẹtísílẹ̀ dáradára.” +Ẹni tí ń ṣọ́nà kígbe pé:“OLUWA mi, lórí ilé-ìṣọ́ ni èmi í dúró sí lojoojumọ,níbi tí a fi mí ṣọ́, ni èmi í sì í wà ní òròòru. +Ẹ wò ó! Àwọn ẹlẹ́ṣin kan ń bọ̀, wọ́n fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ní meji-meji!”“Ẹ gbọ́! Ìlú Babiloni ti wó! Ó ti wó!Pẹlu gbogbo àwọn oriṣa rẹ̀,ó ti wó lulẹ̀ patapata.” +Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerusalẹmu. +Èyí ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa àfonífojì ìran:Kí ni gbogbo yín ń rò tí ẹ fi gun orí òrùlé lọ, +Ẹ ka iye ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu, ẹ sì wó àwọn kan palẹ̀ ninu wọn, kí ẹ lè rí òkúta tún odi ìlú ṣe. +Ẹ wa kòtò sí ààrin ògiri mejeeji, Kí ẹ lè rí ààyè fa omi inú odò àtijọ́ sí. Ṣugbọn ẹ kò wo ojú ẹni tí ó ṣe ohun tí ń ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bìkítà fún ẹni tí ó ṣètò rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ wá. +Ní ọjọ́ náà,OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun fi ìpè sóde pé,kí ẹ máa sọkún, kí ẹ máa ṣọ̀fọ̀,kí ẹ fá orí yín, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora. +Ṣugbọn dípò kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń yọ̀, inú yín ń dùn.Ẹ̀ ń pa mààlúù, ẹ̀ ń pa aguntan,ẹ̀ ń jẹ ẹran, ẹ̀ ń mu ọtí waini.Ẹ̀ ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á jẹ, kí á mu!Nítorí pé lọ́la ni a óo kú.” +OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi tó mi létí pé:“A kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì yíntítí tí ẹ óo fi kú.” +OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní, “Lọ bá Ṣebina, iranṣẹ ọba, tí ó jẹ́ olórí ní ààfin ọba, Kí o bi í pé: +‘Kí ni o fẹ́ máa ṣe níhìn-ín? Ta ni o sì ní níhìn-ín tí o fi gbẹ́ ibojì síhìn-ín fún ara rẹ? Ìwọ tí o gbẹ́ ibojì sórí òkè, tí o kọ́ ilé fún ara rẹ ninu àpáta? +Wò ó! OLUWA yóo fi tipátipá wọ́ ọ sọnù ìwọ alágbára. Yóo gbá ọ mú tipátipá. +Yóo fì ọ́ nàkànnàkàn, yóo sì sọ ọ́ nù bíi bọ́ọ̀lù, sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, níbẹ̀ ni óo kú sí. Níbẹ̀ ni àwọn kẹ̀kẹ́-ogun rẹ tí ó dára yóo wà, ìwọ tí ò ń kó ìtìjú bá ilé OLUWA rẹ. +N óo tì ọ́ kúrò ní ààyè rẹ, n óo fà ọ́ lulẹ̀ kúrò ní ipò rẹ.’ +ẹ̀yin tí ìlú yín kún f��n ariwo, tí ẹ jẹ́ kìkì ìrúkèrúdò ati àríyá?Gbogbo àwọn tí ó kú ninu yín kò kú ikú idà,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú lójú ogun. +“Ní ọjọ́ náà, n óo pe Eliakimu, iranṣẹ mi, ọmọ Hilikaya. +N óo gbé aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n óo sì dì í ní àmùrè rẹ; n óo gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́, yóo sì di baba fún àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda. +N óo fi í ṣe alákòóso ilé Dafidi. Ìlẹ̀kùn tí ó bá ṣí, kò ní sí ẹni tí yóo lè tì í; èyí tí ó bá tì, kò ní sí ẹni tí yóo lè ṣí i. +N óo fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí èèkàn tí a kàn mọ́ ilẹ̀ tí ó le, yóo di ìtẹ́ iyì fún ilé baba rẹ̀. +“Gbogbo ẹbí rẹ̀ ní agboolé baba rẹ̀ yóo di ẹrú rẹ̀, ati àwọn ọmọ ati àwọn ohun èlò, láti orí ife ìmumi, títí kan ìgò ọtí.” +OLUWA àwọn ọmọ-ogun ní, “Ní ọjọ́ náà, èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gbọningbọnin yóo yọ, wọn yóo gé e, yóo sì wó lulẹ̀, ẹrù tí wọn fi kọ́ lórí rẹ̀ yóo sì já dànù.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ. +Gbogbo àwọn ìjòyè ìlú yín parapọ̀ wọ́n sálọ,láì ta ọfà ni ọ̀tá mú wọn.Gbogbo àwọn tí wọn rí ni wọ́n mú,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti sá jìnnà. +Nítorí náà, ni mo ṣe sọ pé,“Ẹ ṣíjú kúrò lára miẹ jẹ́ kí n sọkún, kí n dami lójú pòròpòrò,ẹ má ṣòpò pé ẹ óo rẹ̀ mí lẹ́kún,nítorí ìparun àwọn ará Jerusalẹmu, àwọn eniyan mi.” +Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀,ọjọ́ ìrúkèrúdò ati ìdágìrì ati ìdàrúdàpọ̀, ní àfonífojì ìran.Ọjọ́ wíwó odi ìlú palẹ̀ati igbe kíké láàrin àwọn òkè ńlá. +Àwọn ọmọ ogun Elamu gbé ọfà wọn kọ́ èjìká,pẹlu kẹ̀kẹ́-ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin,àwọn ọmọ ogun Kiri sì tọ́jú asà wọn. +Àwọn àfonífojì dáradára yín kún fún kẹ̀kẹ́-ogunàwọn ẹlẹ́ṣin sì dúró sí ipò wọn lẹ́nu ibodè; +ó ti tú aṣọ lára Juda.Ní ọjọ́ náà, ẹ gbẹ́kẹ̀lé àwọn ohun ìjà tí ó wà ninu Ilé-Igbó, +ẹ rí i pé ibi tí ògiri ìlú Dafidi ti sán pọ̀, ẹ sì gbá omi inú adágún tí ó wà ní ìsàlẹ̀ jọ. +Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire. +Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire nìyí:Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin ọlọ́kọ̀ ojú omi ìlú Taṣiṣi;nítorí pé Tire ti di ahoro,láìsí ilé tabi èbúté!Ní ilẹ̀ Kipru ni a ti fi eléyìí hàn wọ́n. +Ẹ̀yin ará Taṣiṣi,ẹ máa tàn ká orí ilẹ̀ yín títí ẹ ó fi kan odò Naili,kò sí èbúté tí yóo da yín dúró mọ́. +OLUWA ti na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkunÓ ti mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì.Ó ti pàṣẹ nípa ilẹ̀ Kenaanipé kí wọ́n pa gbogbo ibi ààbò rẹ̀ run. +Ó ní, “Àríyá yín ti dópin,ẹ̀yin ọmọ Sidoni tí à ń ni lára.Ò báà dìde kí o lọ sí Kipru,ara kò ní rọ̀ ọ́ níbẹ̀.” +Ẹ wo ilẹ̀ àwọn ará Kalidea! Bí wọ́n ṣe wà bí aláìsí. Àwọn Asiria ti pinnu láti sọ Tire di ibùgbé àwọn ẹranko, wọ́n gbé àkàbà ogun ti odi rẹ̀. Wọ́n fogun kó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀, wọ́n sì sọ ọ́ di ahoro. +Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi, nítorí àwọn ilé ìṣọ́ yín tí ó lágbára ti wó. +Nígbà, tó bá yá, Tire yóo di ìgbàgbé fún aadọrin ọdún gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ ọba kan; lẹ́yìn aadọrin ọdún ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí Tire yóo dàbí orin kan tí àwọn aṣẹ́wó máa ń kọ pé: +“Mú hapu, kí o máa káàkiri ààrin ìlú,ìwọ aṣẹ́wó, ẹni ìgbàgbé.Máa kọ orin dídùn ní oríṣìíríṣìí,kí á lè ranti rẹ.” +Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, OLUWA yóo ranti Tire. Yóo pada sídìí òwò aṣẹ́wó rẹ̀, yóo sì máa bá gbogbo ìjọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe òwò àgbèrè. +Yóo ya ọjà tí ó ń tà ati èrè tí ó bá jẹ sọ́tọ̀ fún OLUWA, kò ní máa to èrè rẹ̀ jọ, tabi kí ó máa kó o pamọ́; ṣugbọn yóo máa lò wọ́n láti pèsè oúnjẹ ati aṣọ fún àwọn tí ó bá ń sin OLUWA. +Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun,ẹ̀yin oníṣòwò ará Sidoni;àwọn iranṣẹ yín ti kọjá sí òdìkejì òkun, +wọ́n gba orí alagbalúgbú omi kọjá lọ.Èrè yín ni ọkà ìlú Sihori,ìkórè etí odò Naili.Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń ṣòwò káàkiri àgbáyé. +Ojú tì ọ́, ìwọ Sidoninítorí òkun ti fọhùn, agbami òkun ti sọ̀rọ̀, ó ní:“N kò rọbí, bẹ́ẹ̀ ni n kò bímọ;n kò tọ́ àwọn ọmọ dàgbà ríkì báà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.” +Nígbà tí ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Tire bá dé Ijiptiàwọn ará Ijipti yóo kérora. +Ẹ kọjá lọ sí Taṣiṣi.Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,ẹ̀yin tí ó ń gbé etí òkun. +Ṣé ìlú olókìkí yín náà nìyí,tí a ti tẹ̀dó láti ìgbà àtijọ́!Tí ó fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,tí ó ṣe àlejò lọ sibẹ! +Ta ni ó gbìmọ̀ irú èyí sí Tire,Ìlú tí ń fún àwọn ọba ìlú yòókù ládé?Tí ó jẹ́ pé kìkì ìjòyè ni àwọn oníṣòwò rẹ̀;gbogbo àwọn tí ń ta ọjà níbẹ̀ ni wọ́n jẹ́ ọlọ́lá ní gbogbo ayé. +OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó pinnu láti ba gbogbo iyì ògo jẹ,ati láti tẹ́ gbogbo àwọn ọlọ́lá ayé. +OLUWA Yóo Jẹ Ilẹ̀ Ayé Níyà. +Ẹ wò ó! OLUWA yóo fọ́ gbogbo ayé wómúwómúyóo sì sọ ọ́ di ahoro.Yóo dojú rẹ̀ rú,yóo sì fọ́n àwọn eniyan inú rẹ̀ ká. +Ìlú ìdàrúdàpọ̀ ti wó palẹ̀, ó ti dòfo,gbogbo ìlẹ̀kùn ilé ti tì, kò sì sí ẹni tí ó lè wọlé. +Ariwo ta lóde nítorí kò sí ọtí waini,oòrùn ayọ̀ ti wọ̀;ayọ̀ di àwátì ní ilẹ̀ náà. +Gbogbo ìlú ti di ahoro,wọ́n ti wó ẹnu ibodè ìlú wómúwómú. +Bẹ́ẹ̀ ní yóo rí ní ilẹ̀ ayé,láàrin àwọn orílẹ̀-èdèbí igi olifi tí a ti gbọn gbogbo èso rẹ̀ sílẹ̀,lẹ́yìn tí a ti kórè tán ninu ọgbà àjàrà. +Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n ń kọrin ayọ̀,wọ́n ń yin OLUWA lógo láti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá. +Nítorí náà ẹ fi ògo fún OLUWA ní ìhà ìlà-oòrùn;ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun,ẹ fògo fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. +Láti òpin ayé ni a ti ń gbọ́ ọpọlọpọ orin ìyìn,wọ́n ń fi ògo fún Olódodo.Ṣugbọn èmi sọ pé:“Mò ń rù, mò ń joro,mò ń joro, mo gbé!Nítorí pé àwọn ọ̀dàlẹ̀ ń dalẹ̀,wọ́n ń dalẹ̀, wọ́n ń hùwà àgàbàgebè.” +Ẹ̀rù ati kòtò, ati tàkúté ń bẹ níwájú yín ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ ayé. +Ẹni tí ẹ̀rù bá bà tí ó sá,yóo já sinu kòtò,ẹni tí ó bá rá pálá jáde ninu kòtòyóo kó sinu tàkúté.Nítorí pé àwọn fèrèsé ojú ọ̀run ti ṣí,àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé sì mì tìtì. +Ayé ti fọ́, ayé ti fàya,ayé sì mì tìtì. +Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará ìlú ni yóo ṣẹlẹ̀ sí alufaa;ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ẹrú yóo ṣẹlẹ̀ sí olówó rẹ̀;ohun tí ó ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ ni yóo ṣe ọ̀gá rẹ̀;ohun tí ó ṣe ẹni tí ń rà ni yóo ṣe ẹni tí ń tà.Ohun tí ó ṣe ẹni tí ń yá ni lówóni yóo ṣe ẹni tí à ń yá lówó.Ohun tí ó ṣe onígbèsè ni yóo ṣe ẹni tí a jẹ lówó. +Ayé ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí,ó ń mì bí abà oko.Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́ lọ́rùn,ó wó lulẹ̀, kò ní dìde mọ́. +Ní àkókò náà,OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ogun ọ̀run, lọ́run;ati àwọn ọba ayé, lórí ilẹ̀ ayé. +A óo gbá gbogbo wọn jọ pọ̀ sinu kòtò bí ẹlẹ́wọ̀n,wọn óo wà ní àtìmọ́lé ninu ẹ̀wọ̀n.Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́, a óo fìyà jẹ wọ́n. +Òṣùpá yóo dààmú,ìtìjú yóo sì bá oòrùn.Nítorí OLUWA àwọn ọmọ-ogun yóo jọbalórí òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu.Yóo sì fi ògo rẹ̀ hànníwájú àwọn àgbààgbà wọn. +Ogun yóo kó ilé ayé,yóo di òfo patapata.Nítorí OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀. +Ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo nǹkan ń rọ.Ayé ń joró, ó sì ń ṣáàwọn ọ̀run ń joró pẹlu. +Àwọn tí ń gbé inú ayé ti ba ilé ayé jẹ́,nítorí pé wọ́n ti rú àwọn òfinwọ́n ti tàpá sí àwọn ìlànàwọ́n sì da majẹmu ayérayé. +Nítorí náà ègún ń pa ayé run lọ.Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,iná ń jó àwọn olùgbé inú rẹ̀,eniyan díẹ̀ ni ó sì kù. +Ọtí waini ń ṣọ̀fọ̀.Igi èso àjàrà ń joró,gbogbo àwọn tí ń ṣe àríyá ti ń kẹ́dùn. +Ìró ìlù ayọ̀ ti dákẹ́,ariwo àwọn alárìíyá ti dópin.Àwọn tí ń tẹ dùùrù ti dáwọ́ dúró. +Wọn kò mu ọtí níbi tí wọ́n ti ń kọrin mọ́ọtí líle sì korò lẹ́nu àwọn tí ń mu ún. +Orin Ìyìn. +OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun mi.N óo gbé ọ ga:n óo yin orúkọ rẹ.Nítorí pé o ti ṣe àwọn nǹkan ìyanu,o ti ṣe àwọn ètò láti ìgbà àtijọ́,o mú wọn ṣẹ pẹlu òtítọ́. +Nítorí OLUWA yóo na ọwọ́ ààbò rẹ̀ sórí òkè yìí. Ṣugbọn àwọn ará Moabu yóo di àtẹ̀mọ́lẹ̀ lórí ilẹ̀ wọ́n, bíi koríko tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ lórí ààtàn. +Wọn óo na ọwọ́ ní ààrin rẹ̀ bí ìgbà tí ẹni tí ń lúwẹ̀ẹ́ bá nawọ́ ninu omi. Ṣugbọn OLUWA yóo rẹ ìgbéraga wọn sílẹ̀, ọwọ́ wọn yóo sì rọ. +OLUWA yóo bi odi gíga rẹ̀ wó, yóo wó o palẹ̀, yóo sì sọ ọ́ di erùpẹ̀ ilẹ̀. +O sọ àwọn ìlú di òkítì àlàpào sì ti pa àwọn ìlú olódi run.O wó odi gíga àwọn àjèjì, kúrò lẹ́yìn ìlú,ẹnikẹ́ni kò sì ní tún un kọ́ mọ́. +Nítorí náà àwọn alágbára yóo máa yìn ọ́ìlú àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú yóo bẹ̀rù rẹ. +Nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi fún talaka,ibi ìsápamọ́sí fún aláìní lákòókò ìṣòro.Ìwọ ni ibi ààbò nígbà òjò,ati ìbòòji ninu oòrùn.Nítorí bí ìjì ti rí lára ògiribẹ́ẹ̀ ni ibinu aláìláàánú rí; +ó dàbí ooru ninu aṣálẹ̀.O pa àwọn àjèjì lẹ́nu mọ́;bí òjìji ìkùukùu tií sé ooru mọ́,bẹ́ẹ̀ ni o ṣe dá orin mọ́ àwọn oníjàgídíjàgan lẹ́nu. +OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo fi àwọn ẹran ọlọ́ràá se àsè kan fún gbogbo orílẹ̀-èdè; yóo pa àwọn ẹran àbọ́pa, pẹlu ọtí waini, ẹran àbọ́pa tí ó sanra, tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ati ọtí waini tí ó dára. +Lórí òkè yìí, OLUWA yóo fa aṣọ tí a ta bo àwọn eniyan lójú ya, àní aṣọ tí a dà bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀. +Yóo gbé ikú mì títí lae, OLUWA yóo nu omijé nù kúrò lójú gbogbo eniyan. Yóo mú ẹ̀gàn àwọn eniyan rẹ̀ kúrò, ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +Wọn óo máa wí ní ọjọ́ náà pé, “Ọlọrun wa nìyí; a ti ń dúró dè é kí ó lè gbà wá, OLUWA nìyí; òun ni a ti ń dúró dè. Ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì dùn nítorí ìgbàlà rẹ̀.” +Orin Ìgbàlà. +Ní àkókò náà,orin tí wọn óo máa kọ ní ilẹ̀ Juda ni pé:“A ní ìlú tí ó lágbára,ó fi ìgbàlà ṣe odi ati ibi ààbò. +Bí a bá ṣàánú ẹni ibi,kò ní kọ́ láti ṣe rere.Yóo máa ṣe ibi ní ilẹ̀ àwọn olódodo,kò sì ní rí ọlá ńlá OLUWA. +OLUWA o ti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti jẹ àwọn ọ̀tá níyà, ṣugbọn wọn kò rí i.Jẹ́ kí wọn rí i péọ̀rọ̀ àwọn eniyan rẹ jẹ ọ́ lógún,kí ojú sì tì wọ́n.Jẹ́ kí iná tí o dá fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run. +OLUWA ìwọ yóo fún wa ní alaafia,nítorí pé ìwọ ni o ṣe gbogbo iṣẹ́ wa fún wa. +OLUWA, Ọlọrun wa,àwọn oluwa mìíràn ti jọba lórí waṣugbọn orúkọ rẹ nìkan ni àwa mọ̀. +Wọ́n ti kú, wọn kò ní wà láàyè mọ́,ẹ̀mí wọn kò ní dìde mọ́ ní isà òkú.Nítorí bẹ́ẹ̀ ni o ṣe jẹ wọ́n níyà,o sì pa wọ́n run,o sì ti sọ gbogbo ìrántí wọn di ohun ìgbàgbé. +Ṣugbọn ìwọ OLUWA ti mú kí orílẹ̀-èdè náà pọ̀ sí i,OLUWA, o ti bukun orílẹ̀-èdè náà,gbogbo ààlà ilẹ̀ náà ni o ti bì sẹ́yìn,o sì ti buyì kún ara rẹ. +OLUWA nígbà tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, wọ́n wá ọ,wọ́n fọkàn gbadura nígbà tí o jẹ wọ́n ní ìyà. +Bí aboyún tí ó fẹ́ bímọ,tí ó ń yí, tí ó sì ń ké ìrora,nígbà tí àkókò àtibímọ rẹ̀ súnmọ́ tòsíbẹ́ẹ̀ ni a rí nítorí rẹ, OLUWA. +A wà ninu oyún, ara ń ro wá,a ní kí a bí, òfo ló jáde.A kò ṣẹgun ohunkohun láyébẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń gbé ayé kò tíì ṣubú. +Àwọn òkú wa yóo jí,wọn óo dìde kúrò ninu ibojì.Ẹ tají kí ẹ máa kọrin,ẹ̀yin tí ó sùn ninu erùpẹ̀.Nítorí pé ìrì ìmọ́lẹ̀ ni ìrì yín,ẹ óo sì sẹ ìrì náà sì ilẹ̀ àwọn òkú. +Ẹ ṣí ìlẹ̀kùn ibodè,kí orílẹ̀-èdè olódodo, tí ń ṣe òtítọ́ lè wọlé. +Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi,ẹ wọ inú yàrá yín,kí ẹ sì ti ìlẹ̀kùn mọ́rí;ẹ farapamọ́ fún ìgbà díẹ̀,títí tí ibinu OLUWA yóo fi kọjá. +OLUWA óo yọ láti ibùgbé rẹ̀,láti fi ìyà jẹ àwọn tí ń gbé inú ayé, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,ilẹ̀ yóo tú ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n pa sórí rẹ̀ jáde,kò sì ní bo àwọn tí a pa mọ́lẹ̀ mọ́. +O óo pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé ọ mọ́ ní alaafia pípé,nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ. +Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA títí lae,nítorí àpáta ayérayé ni OLUWA Ọlọrun. +Ó sọ àwọn tí ń gbé orí òkè kalẹ̀,ó sọ ìlú tí ó wà ní orí òkè téńté di ilẹ̀,ó sọ ọ́ di ilẹ̀ patapata,ó fà á sọ sinu eruku. +Wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,bí àwọn òtòṣì tí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláìní ń tẹ̀ ẹ́.” +Ọ̀nà títẹ́jú ni ọ̀nà àwọn olódodoó mú kí ọ̀nà àwọn olódodo máa dán. +Àwa dúró dè ọ́ ní ọ̀nà ìdájọ́ rẹ, OLUWA,orúkọ rẹ ati ìrántí rẹ ni ọkàn wa ń fẹ́. +Ọkàn mi ń ṣe àfẹ́rí rẹ lálẹ́,mo sì ń fi tọkàntọkàn wá ọnítorí nígbà tí ìlànà rẹ bá wà láyéni àwọn ọmọ aráyé yóo kọ́ òdodo. +Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo fi idà rẹ̀ tí ó mú, tí ó tóbi, tí ó sì lágbára,pa Lefiatani, ejò tí ó ń fò,Lefiatani, ejò tí ń lọ́ wérékéké,yóo sì pa ejò ńlá tí ń bẹ ninu òkun. +Nítorí ìlú olódi ti di ahoro,ó di ibùgbé tí a kọ̀ sílẹ̀, tí a sì patì bí aginjù;ibẹ̀ ni àwọn ọmọ mààlúù yóo ti máa jẹko,wọn óo dùbúlẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì máa jẹ àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀. +Àwọn ẹ̀ka igi náà yóo dánígbà tí wọ́n bá gbẹ,àwọn obinrin yóo sì fi wọ́n dáná.Nítorí òye kò yé àwọn eniyan wọnyi rárá;nítorí náà, ẹni tí ó dá wọn kò ní ṣàánú wọn,Ẹni tí ó mọ wọ́n kò ní yọ́nú sí wọn. +Ní ọjọ́ náà,OLUWA yóo pa ẹ̀yin eniyan Israẹli bí ẹni pa ọkà,láti odò Yufurate títí dé odò Ijipti,yóo sì ko yín jọ lọ́kọ̀ọ̀kan. +Ní ọjọ́ náà,a óo fun fèrè ogun ńlá,àwọn tí ó ti sọnù sí ilẹ̀ Asiriaati àwọn tí a lé lọ sí ilẹ̀ Ijiptiyóo wá sin OLUWA lórí òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu. +Ní ọjọ́ náà,OLUWA yóo kọrin nípa ọgbà àjàrà dáradára kan pé, +“Èmi OLUWA ni olùṣọ́ rẹ̀,lásìkò, lásìkò ni mò ń bomi rin ín;tọ̀sán-tòru ni mò ń ṣọ́ ọkí ẹnìkan má baà bà á jẹ́. +Inú kò bí mi,ǹ bá rí ẹ̀gún ati pàǹtí ninu rẹ̀,ǹ bá gbógun tì wọ́n,ǹ bá jó gbogbo wọn níná papọ̀. +Ṣugbọn bí wọn bá fi mí ṣe ààbò,kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa;kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa.” +Ní ọjọ́ iwájúJakọbu yóo ta gbòǹgbò,Israẹli yóo tanná, yóo rúwé,yóo so, èso rẹ̀ yóo sì kún gbogbo ayé. +Ṣé OLUWA ti jẹ wọ́n níyà bí ó ti fìyà jẹ àwọn tí ó jẹ wọ́n níyà?Ṣé ó ti pa wọ́n bí ó ti pa àwọn tí ó pa wọ́n? +OLUWA fìyà jẹ àwọn eniyan rẹ̀,ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn;ó lé wọn jáde ní ìlú,bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù líle bá ń fẹ́ láti ìlà oòrùn. +Ọ̀nà tí a fi lè pa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu rẹ́,tí a fi lè mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò ni pé:Kí ó fọ́ gbogbo òkúta àwọn pẹpẹ oriṣa rẹ̀ túútúú,bí ẹfun tí a lọ̀ kúnná;kí ó má ku ère oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari kan lóòró. +Ìkìlọ̀ fún Ilẹ̀ Israẹli. +Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efuraimu gbé!Ẹwà ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí ìtànná náà gbé!Ìlú tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,ohun àmúyangàn fún àwọn tí ó mutí yó. +Nítorí pé gbogbo rẹ̀ tòfin-tòfin ni,èyí òfin, tọ̀hún ìlànà.Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún.” +Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àjèjì tí èdè wọn yàtọ̀ ni OLUWA yóo lòláti bá àwọn eniyan wọnyi sọ̀rọ̀. +Àwọn tí ó ti wí fún pé: Ìsinmi nìyí,ẹ fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní ìsinmi;ìtura nìyí.Sibẹsibẹ wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́. +Nítorí náà ọ̀rọ̀ OLUWA sí wọn yóo jẹ́ tòfin-tòfin,èyí òfin tọ̀hún ìlànà.Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún,kí wọ́n baà lè lọ ṣubú sẹ́yìnkí wọ́n sì fọ́ wẹ́wẹ́;kí á lè dẹ tàkúté sílẹ̀ fún wọn,kí ọwọ́ lè tẹ̀ wọ́n. +Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,ẹ̀yin oníyẹ̀yẹ́ eniyan,tí ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi ní Jerusalẹmu. +Nítorí ẹ wí pé: “A ti bá ikú dá majẹmu,a sì ti bá ibojì ṣe àdéhùn.Nígbà tí jamba bá ń bọ̀,kò ní dé ọ̀dọ̀ wa;nítorí a ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa,a sì ti fi èké ṣe ibi ààbò.” +Nítorí náà OLUWA Ọlọrun sọ pé, “Wò ó! Èmi yóo ri òkúta ìpìlẹ̀ ilé kan mọ́lẹ̀ ní Sioni,yóo jẹ́ òkúta tí ó lágbára,òkúta igun ilé iyebíye, tí ó ní ìpìlẹ̀ tí ó dájú:Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, ojú kò níí kán an. +Ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ni n óo fi ṣe okùn ìwọnlẹ̀,òdodo ni n óo fi ṣe ìwọ̀n ògiri.”Òjò àdàpọ̀ mọ́ yìnyín yóo gbá ibi ààbò irọ́ dànù,omi yóo sì bo ibi tí wọ́n sápamọ́ sí. +Majẹmu tí ẹ bá ikú dá yóo wá di òfo,àdéhùn yín pẹlu ibojì yóo sì di asán.Nígbà tí jamba bá ń ṣẹlẹ̀ káàkiri,yóo máa dé ba yín. +Gbogbo ìgbà tí ó bá ti ń ṣẹlẹ̀ni yóo máa ba yín tí yóo máa gba yín lọ.Yóo máa ṣẹlẹ̀ láàárọ̀,yóo sì máa ṣẹlẹ̀ tọ̀sán-tòru.Ẹ̀rù yóo ba eniyan,tí eniyan bá mọ ìtumọ̀ ìkìlọ̀ náà. +Wò ó! OLUWA ní ẹnìkan,tí ó lágbára bí ẹ̀fúùfù líle, ati bí ìjì apanirun,bí afẹ́fẹ́ òjò tí ó lágbáratí àgbàrá rẹ̀ ṣàn kọjá bèbè;ẹni náà yóo bì wọ́n lulẹ̀. +Ibùsùn kò ní na eniyan tán.Bẹ́ẹ̀ ni aṣọ ìbora kò ní fẹ̀ tó eniyan bora. +Nítorí pé OLUWA yóo dìde bí ó ti ṣe ní òkè Firasi,yóo bínú bí ó ti bínú ní àfonífojì Gibeoni.Yóo ṣe ohun tí ó níí ṣe,ohun tí yóo ṣe yóo jọni lójú;yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀iṣẹ́ rẹ̀ yóo ṣe àjèjì. +Nítorí náà ẹ má ṣe yẹ̀yẹ́,kí á má baà so ẹ̀wọ̀n yín le.Nítorí mo ti gbọ́ ìkéde ìparun,tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti mú wá sórí ilẹ̀ ayé. +Ẹ fetí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ohùn mi,ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, +ṣé ẹni tí ń kọ ilẹ̀ tí ó fẹ́ gbin ohun ọ̀gbìnlè máa kọ ọ́ lọ láì dáwọ́ dúró?Àbí ó lè máa kọ ebè lọ láì ní ààlà? +Ṣugbọn bí ó bá ti tọ́jú oko rẹ̀ tán,ṣé kò ní fọ́n èso dili ati èso Kumini sinu rẹ̀,kí ó gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ;kí ó gbin ọkà baali sí ibi tí ó yẹ,kí ó sì gbin oríṣìí ọkà mìíràn sí ààlà oko rẹ̀? +Yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ létòlétò bí ó ti yẹ,nítorí pé Ọlọrun rẹ̀ ní ń kọ́ ọ. +��gbẹ̀ kì í fi òkúta ńlá ṣẹ́ ẹ̀gúsí,bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi kùmọ̀, lu kumini.Ọ̀pá ni wọ́n fí ń lu ẹ̀gúsí;igi lásán ni wọ́n fí ń lu kumini. +Ǹjẹ́ eniyan a máa fi kùmọ̀ lọ ọkà alikama tí wọ́n fi ń ṣe burẹdi?Rárá, ẹnìkan kì í máa pa ọkà títí kí ó má dáwọ́ dúró.Bó ti wù kí eniyan fi ẹṣin yí ẹ̀rọ ìpakà lórí ọkà alikama tó,ẹ̀rọ ìpakà kò lè lọ ọkà kúnná. +Ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ìmọ̀ yìí ti ń wá pẹlu,ìmọ̀ràn rẹ̀ yani lẹ́nu;ọgbọ́n rẹ̀ ni ó sì ga jùlọ. +Ẹsẹ̀ ni yóo fi tẹ adé ìgbéragaàwọn ọ̀mùtí ilẹ̀ Efuraimu. +Ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí òdòdótí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,yóo dàbí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́,tí ó pọ́n ṣáájú ìgbà ìkórè.Ẹni tó bá rí i yóo sáré sí i,yóo ká a, yóo sì jẹ ẹ́. +Ní ọjọ́ náà,OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo jẹ́ adé ògo ati adé ẹwà,fún àwọn tí ó kù ninu àwọn eniyan rẹ̀. +Yóo jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ ẹ̀tọ́fún adájọ́ tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́,yóo jẹ́ agbára fún àwọn tí ó ń lé ogun sẹ́yìn lẹ́nu ibodè. +Ọtí waini ń ti àwọn wọnyi,ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.Ọtí líle ń ti alufaa ati wolii,ọtí waini kò jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́.Ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n;wọ́n ń ríran èké, wọ́n ń dájọ́ irọ́. +Nítorí èébì kún orí gbogbo tabili oúnjẹ,gbogbo ilẹ̀ sì kún fún ìdọ̀tí +Wọ́n ń sọ pé, “Ta ni yóo kọ́ lọ́gbọ́n?Ta sì ni yóo jíṣẹ́ náà fún?Ṣé àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọyàn lẹ́nu wọn,àbí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú? +Òkè Sioni Ìlú Dafidi. +Ó ṣe fún Arieli, Jerusalẹmu, ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun!Ìlú tí Dafidi pàgọ́ sí.Ẹ ṣe ọdún kan tán, ẹ tún ṣe òmíràn sí i,ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún ní gbogbo àkókò wọn. +Nítorí OLUWA ti fi ẹ̀mí oorun àsùnwọra si yín lára Ó ti di ẹ̀yin wolii lójú;ó ti bo orí ẹ̀yin aríran. +Gbogbo ìran yìí sì ru yín lójú,bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a fi èdìdì dì.Nígbà tí wọ́n gbé e fún ọ̀mọ̀wétí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.”Ó ní òun kò lè kà ánítorí pé wọ́n ti fi èdìdì dì í. +Nígbà tí wọ́n gbé e fún ẹni tí kò mọ̀wétí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.”Ó ní òun kò mọ̀wé kà. +OLUWA ní, “Nítorí pé ẹnu nìkan ni àwọn eniyan wọnyi fi ń súnmọ́ mi,ètè lásán ni wọ́n sì fi ń yìn mí;ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi.Òfin eniyan, tí wọn kọ́ sórí lásán, ni ìbẹ̀rù mi sì jẹ́ fún wọn. +Nítorí náà n óo tún ṣe ohun ìyanu sí àwọn eniyan wọnyi, ohun ìyanu tí ó jọni lójú.Ọgbọ́n yóo parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu,ìmọ̀ràn yóo sì parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀mọ̀ràn níkùn.” +Àwọn tí wọ́n fi èrò wọn pamọ́ fún OLUWA gbé;àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ́ iṣẹ́ òkùnkùn,tí ń wí pé, “Ta ló rí wa?Ta ló mọ̀ wá?” +Ẹ dorí gbogbo nǹkan kodò. Ṣé eniyan lè sọ amọ̀kòkò di amọ̀?Kí nǹkan tí eniyan ṣe, wí nípa ẹni tí ó ṣe é pé:“Kìí ṣe òun ló ṣe mí.”Tabi kí nǹkan tí eniyan dá sọ nípa ẹni tí ó dá a pé:“Kò ní ìmọ̀.” +Ṣebí díẹ̀ ṣínún ló kùtí a óo sọ Lẹbanoni di ọgbà igi elésoa óo sì máa pe ọgbà igi eléso náà ní igbó. +Ní ọjọ́ náà, odi yóo gbọ́ ohun tí a kọ sinu ìwé,ojú afọ́jú yóo ríran, ninu òkùnkùn biribiri rẹ̀. +Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo tún láyọ̀ láti ọ̀dọ̀ OLUWA.Àwọn aláìní yóo máa yọ̀ ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli +Sibẹsibẹ n óo mú ìpọ́njú bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun.Ìkérora ati ìpohùnréré ẹkún yóo wà ninu rẹ̀,bíi Arieli ni yóo sì rí sí mi. +nítorí pé àwọn aláìláàánú yóo di asán,àwọn apẹ̀gàn yóo di òfo;àwọn tí ń wá ọ̀nà láti ṣe ibi yóo parun; +àwọn tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ eniyan di ẹlẹ́ṣẹ̀,tí ń dẹ tàkúté sílẹ̀ fún ẹni tí ń tọ́ni sọ́nà,tí wọ́n sì ń fi àbòsí tí kò nídìí ti olódodo sí apá kan. +Nítorí náà, OLUWA tí ó ra Abrahamu pada sọ nípa ilé Jakọbu pé,“Ojú kò ní ti Jakọbu mọ́bẹ́ẹ̀ ni ojú rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì mọ́. +Nítorí nígbà tí ó bá rí àwọn ọmọ rẹ̀,tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ mi láàrin wọn,wọn óo fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi.Wọn óo bọ̀wọ̀ fún Ẹni Mímọ́ Jakọbu;wọn óo sì bẹ̀rù Ọlọrun Israẹli. +Àwọn tí ó ti ṣìnà ninu ẹ̀mí yóo ní òye;àwọn tí ń kùn yóo sì gba ẹ̀kọ́.” +N óo jẹ́ kí ogun dó tì yín yíkán óo fi àwọn ilé ìṣọ́ ka yín mọ́;n óo sì mọ òkítì sára odi yín. +Ninu ọ̀gbun ilẹ̀ ni a óo ti máa gbóhùn rẹ̀,láti inú erùpẹ̀ ni a óo ti máa gbọ́, tí yóo máa sọ̀rọ̀.A óo máa gbọ́ ohùn rẹ̀ láti inú ilẹ̀ bí ohùn òkú,a óo sì máa gbọ́ tí yóo máa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ láti inú erùpẹ̀. +Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo pọ̀ bí iyanrìn,ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìláàánú yóo bò ọ́ bí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ. +Lójijì, kíá,OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dé ba yín,pẹlu ààrá, ati ìdágìrì, ati ariwo ńlá;ati ààjà, ati ìjì líle,ati ahọ́n iná ajónirun. +Ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun jà,yóo parẹ́ bí àlá,gbogbo àwọn tí ń bá ìlú olódi rẹ jà,tí wọn ń ni í lára yóo parẹ́ bí ìran òru. +Bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa bá lá àlá pé òun ń jẹun,tí ó jí, tí ó rí i pé ebi sì tún pa òun,tabi tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ́ lá àlápé òun ń mu omiṣugbọn tí ó jí, tí ó rí i pé òùngbẹ ṣì ń gbẹ òun,bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ogunlọ́gọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá Jerusalẹmu jà. +Ẹ sọ ara yín di òmùgọ̀,kí ẹ sì máa ṣe bí òmùgọ̀.Ẹ fọ́ ara yín lójúkí ẹ sì di afọ́jú.Ẹ mu àmuyó, ṣugbọn kì í ṣe ọtí.Ẹ máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láì mu ọtí líle. +Ìdàrúdàpọ̀ Ní Jerusalẹmu. +Wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo múgbogbo àwọn tí àwọn eniyan gbójúlé kúrò,ati àwọn nǹkan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ní Jerusalẹmu ati Juda.Yóo gba gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbójúlé,ati gbogbo omi tí wọ́n fi ẹ̀mí tẹ̀. +Sọ fún àwọn olódodo pé yóo dára fún wọnnítorí wọn yóo jèrè iṣẹ́ wọn. +Ègbé ni fún àwọn eniyan burúkú,kò ní dára fún wọn.Nítorí wọn óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn. +Ẹ wá wo àwọn eniyan mi!Ọmọde ni àwọn olórí àwọn eniyan mi;àwọn obinrin ní ń pàṣẹ lé wọn lórí.Ẹ̀yin eniyan mi,àwọn olórí yín ń ṣì yín lọ́nà,wọ́n sì ti da ọ̀nà yín rú. +OLUWA ti dìde láti ro ẹjọ́ tirẹ̀;ó ti múra tán láti dá àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́jọ́ +OLUWA yóo pe àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí àwọn eniyan rẹ̀siwaju ìtẹ́ ìdájọ́,yóo sọ fún wọn pé;“Ẹ̀yin ni ẹ jẹ ọgbà àjàrà mi run,ohun tí ẹ jí nílé àwọn talaka ń bẹ nílé yín. +Kí ni ẹ rò tí ẹ fi ń tẹ àwọn eniyan mi ní àtẹ̀rẹ́,tí ẹ̀ ń fi ojú àwọn talaka gbolẹ̀?” +OLUWA ní,“Nítorí pé àwọn obinrin Jerusalẹmu jẹ́ onigbeeraga,bí wọn bá ń rìn, wọn á gbé ọrùn sókè gangan;wọn á máa ṣẹ́jú bí wọn tí ń yan lọ.Ṣaworo tí ó wà lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn a sì máa dúnbí wọ́n tí ń gbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. +OLUWA yóo mú kí orí àwọn obinrin Jerusalẹmu pá;yóo ṣí aṣọ lórí wọn.” +Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo já gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ wọn dànù; ati ṣaworo ẹsẹ̀ wọn ni, ati ẹ̀gbà orí wọn; ẹ̀gbà ọrùn wọn; +ati yẹtí wọn, ẹ̀gbà ọwọ́ wọn ati ìbòrí wọn. +Yóo mú àwọn alágbára ati àwọn ọmọ ogun kúrò,pẹlu àwọn onídàájọ́ ati àwọn wolii,àwọn aláfọ̀ṣẹ ati àwọn àgbààgbà; +Gèlè wọn ati ìlẹ̀kẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, ati ìborùn, ìgò ìpara wọn ati òògùn, +òrùka ọwọ́ wọn ati òrùka imú, +ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ati ẹ̀wù àwọ̀lékè ati aṣọ wọn, ati àpò +ati àwọn aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, àwọn ìborùn olówó ńlá. +Òórùn burúkú yóo wà dípò òórùn dídùn ìpara,okùn yóo wà dípò ọ̀já;orí pípá yóo dípò irun tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́,aṣọ ọ̀fọ̀ yóo dípò aṣọ olówó iyebíye.Ìtìjú yóo bò yín dípò ẹwà. +Idà ni yóo pa àwọn ọkunrin yín,àwọn akikanju yín yóo kú sógun. +Ọ̀fọ̀ ati ẹkún yóo pọ̀ ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu.Yóo dàbí obinrin tí wọ́n tú sí ìhòòhò,tí ó jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀. +àwọn olórí aadọta ọmọ ogun, ati àwọn ọlọ́lá,àwọn adáhunṣe ati àwọn pidánpidán, ati àwọn olóògùn. +Ọdọmọkunrin ni OLUWA yóo fi jẹ olórí wọn,àwọn ọmọde ni yóo sì máa darí wọn. +Àwọn eniyan náà yóo máa fìyà jẹ ara wọn,olukuluku yóo máa fìyà jẹ ẹnìkejì rẹ̀,àwọn aládùúgbò yóo sì máa fìyà jẹ ara wọn.Ọmọde yóo nàró mọ́ àgbàlagbà,àwọn mẹ̀kúnnù yóo máa dìde sí àwọn ọlọ́lá. +Nígbà tí ẹnìkan bá dì mọ́ arakunrin rẹ̀,ninu ilẹ̀ baba rẹ̀, tí ó sọ fún un pé,“Ìwọ ní aṣọ ìlékè,nítorí náà, jẹ́ olórí fún wa;gbogbo ahoro yìí yóo sì wà lábẹ́ àkóso rẹ.” +Ní ọjọ́ náà, ẹni tí wọn sọ pé kí ó jẹ olórí yóo kígbe pé,“Èmi kò ní jẹ oyè alátùn-únṣe.N kò ní oúnjẹ nílébẹ́ẹ̀ ni kò sí aṣọ.Ẹ má fi mí ṣe olórí yín.” +Nítorí Jerusalẹmu ti kọsẹ̀,Juda sì ti ṣubú.Nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ati ìṣe wọn lòdì sí OLUWA,wọ́n ń tàpá s�� ògo wíwà rẹ̀. +Ìwà àgàbàgebè wọn ń takò wọ́n;wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bíi ti Sodomu:Wọn kò fi bò rárá.Ègbé ni fún wọn,nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibi wá sórí ara wọn. +Àdéhùn tí kò Wúlò pẹlu Ijipti. +OLUWA ní:“Àwọn ọmọ aláìgbọràn gbé.Àwọn tí wọn ń dá àbá tí ó yàtọ̀ sí tèmi,tí wọn ń kó ẹgbẹ́ jọ,ṣugbọn tí kìí ṣe nípa ẹ̀mí mi;kí wọ́n lè máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀. +Wọ́n á máa sọ fún àwọn aríran pé,“Ẹ má ríran mọ.”Wọ́n á sì máa sọ fún àwọn wolii pé,“Ẹ má sọ àsọtẹ́lẹ̀ òtítọ́ fún wa mọ́,ọ̀rọ̀ dídùn ni kí ẹ máa sọ fún wa,kí ẹ sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn fún wa. +Ẹ fi ojú ọ̀nà sílẹ̀, ẹ yà kúrò lójú ọ̀nà,ẹ má sọ nípa Ẹni Mímọ́ Israẹli fún wa mọ́.” +Nítorí náà, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní:“Nítorí pé ẹ kẹ́gàn ọ̀rọ̀ yìí,ẹ gbẹ́kẹ̀lé ìninilára ati ẹ̀tàn,ẹ sì gbára lé wọn, +nítorí náà, ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dá yìí;yóo dàbí ògiri gíga tí ó là, tí ó sì fẹ́ wó;lójijì ni yóo wó lulẹ̀ lẹ́ẹ̀kanṣoṣo. +Wíwó rẹ̀ yóo dàbí ìgbà tí eniyan la ìkòkò mọ́lẹ̀,tí ó fọ́ yángá-yángá,tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò rí àpáàdì kan mú jáde ninu rẹ̀,tí a lè fi fọn iná ninu ààrò,tabi èkúfọ́, tí a lè fi bu omi ninu odò.” +Nítorí OLUWA Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní:“Bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì farabalẹ̀,ẹ óo rí ìgbàlà;bí ẹ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun,ẹ óo lágbára.Ṣugbọn ẹ kọ̀. +Ẹ sọ pé ó tì o, ẹ̀yin óo gun ẹṣin sálọ ni.Nítorí náà sísá ni ẹ óo sálọ.Ẹ sọ pé ẹṣin tí ó lè sáré ni ẹ óo gùn.Nítorí náà àwọn tí yóo máa le yín,wọn óo lè sáré gan-an ni. +Ẹgbẹrun ninu yín yóo sá fún ẹyọ ọ̀tá yín kan,gbogbo yín yóo sì sá fún ẹyọ eniyan marun-untítí tí àwọn tí yóo kú ninu yín yóo fi dàbí igi àsíá lórí òkè.Wọn óo dàbí àsíá ati àmì lórí òkè.” +Nítorí náà OLUWA ń dúró dè yín,ó ti ṣetán láti ṣàánú yín.Yóo dìde, yóo sì ràn yín lọ́wọ́.Nítorí Ọlọrun Olódodo ni OLUWA. +Ẹ̀yin ará Sioni tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ kò ní sọkún mọ́. OLUWA yóo ṣàánú yín nígbà tí ẹ bá ké pè é, yóo sì da yín lóhùn nígbà tí ó bá gbọ́ igbe yín. +Wọ́n múra, wọ́n gbọ̀nà Ijiptiláì bèèrè ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ mi.Wọ́n lọ sápamọ́ sí abẹ́ ààbò Farao,wọ́n lọ wá ààbò ní Ijipti. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ ní ọpọlọpọ ìṣòro, yóo sì jẹ́ kí ẹ ṣe ọpọlọpọ wahala, sibẹsibẹ olùkọ́ yín kò ní farapamọ́ fun yín mọ́, ṣugbọn ẹ óo máa fi ojú yín rí i. +Bí ẹ bá fẹ́ yapa sí apá ọ̀tún tabi apá òsì, ẹ óo máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn yín tí yóo máa wí pé, “Ọ̀nà nìyí, ibí ni kí ẹ gbà.” +Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!” +OLUWA yóo sì fi òjò ibukun sí orí èso tí ẹ gbìn sinu oko, nǹkan ọ̀gbìn yín yóo sì so lọpọlọpọ. Ní àkókò náà, àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí yóo máa jẹ ní pápá oko yóo pọ̀. +Àwọn mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ fí ń ṣe iṣẹ́ lóko yóo máa jẹ oko tí a fi iyọ̀ sí; tí a ti gbọn ìdọ̀tí kúrò lára rẹ̀. +Omi yóo máa ṣàn jáde láti orí gbogbo òkè gíga ati gbogbo òkè ńlá, ní ọjọ́ tí ọpọlọpọ yóo kú, nígbà tí ilé ìṣọ́ bá wó lulẹ̀. +Òṣùpá yóo mọ́lẹ̀ bí oòrùn; oòrùn yóo mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po meje, ní ọjọ́ tí OLUWA yóo bá di ọgbẹ́ àwọn eniyan rẹ̀, tí yóo sì wo ọgbẹ́ tí ó dá sí wọn lára sàn. +Ẹ wo OLUWA tí ń bọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè,ó ń bọ̀ tìbínú-tìbínú;ninu èéfín ńlá tí ń lọ sókè.Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kún fún ibinu;ahọ́n rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni run. +Èémí rẹ̀ dàbí odò tí ó ṣàn kọjá bèbè rẹ̀tí ó lè mu eniyan dé ọrùn.Yóo fi ajọ̀ ìparun jọ àwọn orílẹ̀-èdè,yóo sì fi ìjánu tí ń múni ṣìnà bọ àwọn eniyan lẹ́nu. +Ẹ óo kọ orin kan bí orin alẹ́ ọjọ́ àjọ̀dún mímọ́,inú yín yóo sì dùn bíi ti ẹni tí ń jó ijó fèrè lọsórí òkè OLUWA, àpáta Israẹli. +Nítorí náà, ààbò Farao yóo di ìtìjú fún wọn,ibi ìpamọ́ abẹ́ Ijipti yóo di ìrẹ̀sílẹ̀ fún wọn. +OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ó lógo,yóo sì jẹ́ kí ẹ rí ọwọ́ rẹ̀ tí yóo fà yọ pẹlu ibinu ńláati ninu iná ajónirun;pẹlu ẹ̀fúùfù ati ìjì líle ati òjò yìnyín. +Ìbẹ̀rù-bojo yóo mú àwọn ará Asirianígbà tí wọ́n bá gbóhùn OLUWA,nígbà tí ó bá fi kùmọ̀ rẹ̀ lù wọ́n. +Ìró ọ̀pá tí OLUWA yóo fi nà wọ́n yóo dàbí ìró aro ati dùùrù.OLUWA yóo dojú ogun kọ wọ́n. +Nítorí pé a ti pèsè iná ìléru sílẹ̀ láti ìgbà àtijọ́ fún ọba Asiria;iná ńlá tí ń jó pẹlu ọpọlọpọ igi.Èémí OLUWA tó dàbí ìṣàn imí-ọjọ́ ni yóo ṣá iná sí i. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olórí wọn ti lọ sí Soani,tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé Hanesi. +Ojú yóo tì wọ́n, nítorí wọn ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kò lè ràn wọ́n lọ́wọ́.Wọn kò lè rí ìrànwọ́ tabi anfaani kankan níbẹ̀, bíkòṣe ìtìjú ati ẹ̀gàn.” +Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹranko ilẹ̀ Nẹgẹbu nìyí:“Wọ́n di àwọn nǹkan ìní wọn sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,wọ́n sì di ìṣúra wọn sí ẹ̀yìn ràkúnmí.Wọ́n ń la ilẹ̀ ìṣòro ati wahala kọjá.Ilẹ̀ àwọn akọ kinniun ati abo kinniun,ilẹ̀ paramọ́lẹ̀ ati ejò amúbíiná tí ń fò.Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan tí kò lè ṣe wọ́n ní anfaani. +Nítorí ìmúlẹ̀mófo ni ìrànwọ́ Ijipti.Nítorí náà ni mo ṣe pè é ní,‘Rahabu tí ń jókòó lásán.’ ” +Nisinsinyii lọ kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú wọn,kí o sì kọ ọ́ sinu ìwé,kí ó lè wà títí di ẹ̀yìn ọ̀la,gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí lae; +nítorí aláìgbọràn eniyan ni wọ́n,Òpùrọ́ ọmọ tí kìí fẹ́ gbọ́ ìtọ́ni OLUWA. +Ọlọrun Yóo Dáàbò Bo Jerusalẹmu. +Àwọn tí ó ń lọ sí Ijipti fún ìrànlọ́wọ́ gbé!Àwọn tí wọ́n gbójú lé ẹṣin;tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun nítorí pé wọ́n pọ̀,tí wọ́n gbójú lé ẹṣinnítorí pé wọ́n lágbára!Wọn kò gbójú lé Ẹni Mímọ́ Israẹli,wọn kò sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA. +Bẹ́ẹ̀ ni ó gbọ́n,ó sì mọ ọ̀nà tí ó fi lè mú kí àjálù dé bá eniyan,kì í sọ̀rọ̀ tán, kó yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada.Ṣugbọn yóo dìde sí ìdílé àwọn aṣebi,ati àwọn tí ń ti àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn. +Eniyan sá ni àwọn ará Ijipti,wọn kìí ṣe Ọlọrun.Ẹranko lásán sì ni ẹṣin wọnwọn kì í ṣe àǹjọ̀nnú.Bí OLUWA bá na ọwọ́, tí ó bá gbá wọn mú,ẹni tí ń ranni lọ́wọ́ yóo fẹsẹ̀ kọ,ẹni tí à ń ràn lọ́wọ́ yóo ṣubú;gbogbo wọn yóo sì jọ ṣègbé pọ̀. +Nítorí OLUWA sọ fún mi pé,“Bí kinniun tabi ọmọ kinniunti máa ń kùn lórí ẹran tí ó bá pa,tí kìí bìkítà fún igbe àwọn olùṣọ́ aguntan,tí wọ́n pera wọn jọ, tí wọn ń bọ̀,tí ẹ̀rù ariwo wọn kìí sìí bà á;bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo sọ̀kalẹ̀,yóo wá jà lórí òkè Sioni ati àwọn òkè tí ó yí Sioni ká. +Bí àwọn ẹyẹ tií da ìyẹ́ bo ìtẹ́ wọn,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogunyóo dáàbò bo Jerusalẹmu,yóo dáàbò bò ó, yóo sì gbà á sílẹ̀yóo dá a sí, yóo sì yọ ọ́ kúrò ninu ewu.” +Ẹ̀yin ọmọ Israẹli,ẹ pada sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣàìgbọràn sí lọpọlọpọ. +Nítorí pé ní ọjọ́ náà, olukuluku yóo gbé àwọn ère fadakaati ère wúrà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe sọnù,àwọn ère tí ó mú wọn dẹ́ṣẹ̀. +Idà ni yóo pa Asiria, ṣugbọn kì í ṣe láti ọwọ́ eniyan;idà tí kò ní ọwọ́ eniyan ninu ni yóo pa á run.Yóo sá lójú ogun,a óo sì kó àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lọ máa ṣiṣẹ́ tipátipá. +Ẹ̀rù yóo ba ọba Asiria, yóo sálọ.Ìpayà yóo mú kí àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ju àsíá sílẹ̀.OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀,OLUWA tí iná rẹ̀ wà ní Sioni,tí ojú ààrò rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu. +Ọba tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. +Wò ó! Ọba kan yóo jẹ pẹlu òdodo,àwọn ìjòyè yóo sì máa ṣe àkóso pẹlu ẹ̀tọ́. +Ní nǹkan bíi ọdún kan ó lé díẹ̀ sí iẹ̀yin obinrin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra; ẹ ó rí ìdààmúnítorí pé àkókò ìkórè yóo kọjá,èso àjàrà kò sì ní sí lórí igi mọ́. +Ẹ gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀,kí wahala ba yín, ẹ̀yin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra,ẹ tú aṣọ yín, kí ẹ wà ní ìhòòhò;kí ẹ sì ró aṣọ ọ̀fọ̀. +Ẹ káwọ́ lérí, kí ẹ káàánú nítorí àwọn oko dáradára,ati nítorí àwọn àjàrà eléso; +nítorí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n ati ẹ̀gún ọ̀gàn ni ó ń hù lórí ilẹ̀ àwọn eniyan mi.Bákan náà, ẹ káàánú fún àwọn ilé aláyọ̀ ninu ìlú tí ó kún fún ayọ̀, +nítorí pé àwọn eniyan yóo sá kúrò ní ààfin,ìlú yóo tú, yóo di ahoro.Òkè ati ilé ìṣọ́ yóo di ibùgbé àwọn ẹranko títí lae,yóo di ibi ìgbádùn fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́,ati pápá ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn. +Bẹ́ẹ̀ ni nǹkan yóo rí,títí ẹ̀mí óo fi bà lé wa láti òkè ọ̀run wátítí aṣálẹ̀ yóo fi di ọgbà eléso,tí ọgbà eléso yóo sì fi di igbó. +A ��o máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ní gbogbo ilẹ̀ náà,ìwà òdodo yóo sì wà níbi gbogbo. +Àyọrísí òdodo yóo sì jẹ́ alaafia,ìgbẹ̀yìn rẹ̀ yóo sì jẹ́ ìbàlẹ̀ àyà wa,ati igbẹkẹle OLUWA títí lae. +Àwọn eniyan mi yóo máa gbé pẹlu alaafia,ní ibùgbé tí ó ní ààbò ati ibi ìsinmi tí ó ní ìbàlẹ̀ àyà. +Yìnyín yóo bọ́, yóo bo gbogbo ilẹ̀,a óo sì pa ìlú náà run patapata. +Olukuluku yóo dàbí ibi ààbò nígbà tí ẹ̀fúùfù bá ń fẹ́ati ibi ìsásí nígbà tí ìjì bá ń jàWọ́n óo dàbí odò ninu aṣálẹ̀,ati bí ìbòòji àpáta ńlá nílẹ̀ olóoru. +Ayọ̀ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fúnrúgbìn sí etí odò yóo pọ̀,ẹ̀yin tí ẹ ní mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ń jẹ káàkiri. +Àwọn tí wọ́n bá rí i kò ní dijú sí i,etí àwọn tí ó gbọ́ ọ kò ní di. +Àwọn tí kò ní àròjinlẹ̀ tẹ́lẹ̀ yóo ní òye,àwọn akólòlò yóo sì sọ̀rọ̀ ketekete. +A kò ní máa pe aláìgbọ́n ní ọlọ́lá mọ́,bẹ́ẹ̀ ni a kò ní máa pe abàlújẹ́ ní eniyan pataki. +Nítorí pé aláìgbọ́n ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,ọkàn rẹ̀ sì ń pète ibi.Ó ń ro bí yóo ṣe hùwà ẹni tí kò mọ Ọlọrun,tí yóo sọ̀rọ̀ ìsọkúsọ sí OLUWA;tí yóo fi ẹni tí ebi ń pa sílẹ̀, láì fún un ní oúnjẹ,tí yóo sì fi omi du ẹni òùngbẹ ń gbẹ. +Kìkì ibi ni èrò inú àwọn eniyankeniyan.Wọn a máa pète ìkà,láti fi irọ́ pa àwọn talaka run,kì báà jẹ́ pé ẹjọ́ aláìní jàre. +Ṣugbọn eniyan rere a máa ro èrò rere,ìdí nǹkan rere ni à á sì í bá wọn. +Ẹ dìde, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀,ẹ gbóhùn mi; ẹ̀yin ọmọbinrin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra,ẹ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi. +Adura fún Ìrànlọ́wọ́. +O gbé! Ìwọ tí ń panirun,tí ẹnìkan kò parun,ìwọ tí ò ń hùwà ọ̀dàlẹ̀nígbà tí ẹnìkan kò dà ọ́.Ìgbà tí o bá dáwọ́ ìpanirun dúró,nígbà náà ni a óo pa ìwọ gan-an run;nígbà tí o bá fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ sílẹ̀,nígbà náà ni a óo dà ọ́. +OLUWA ní:“Ó yá tí n óo dìde,ó yá mi wàyí, n óo gbéra nílẹ̀.Àsìkò tó tí a óo gbé mi ga. +Èrò yín dàbí fùlùfúlù, gbogbo ìṣe yín dàbí pòpórò ọkà.Èémí mi yóo jó yín run bí iná. +Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dàbí ìgbà tí a sun wọ́n,tí wọ́n di eérú,àní bí igi ẹ̀gún tí a gé lulẹ̀, tí a sì dáná sun. +Ẹ̀yin tí ẹ wà lókè réré,ẹ gbọ́ ohun tí mo ṣe;ẹ̀yin tí ẹ wà nítòsí,ẹ kíyèsí agbára mi.” +Ẹ̀rù ń ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó wà ní Sioni;ìjayà mú àwọn ẹni tí kò mọ Ọlọrun.Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná ajónirun?Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná àjóòkú? +Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, tí ó sì ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́,ẹni tí ó kórìíra èrè àjẹjù,tí ó kọ̀, tí kò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí ó di etí sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ń gbèrò ati paniyan,tí ó sì di ojú rẹ̀ kí ó má baà rí nǹkan ibi. +Ibi ààbò ni yóo máa gbé, àpáta ńlá ni yóo jẹ́ ibi ààbò rẹ̀.Yóo máa rí oúnjẹ jẹ déédé,yóo sì máa rí omi mu lásìkò, lásìkò. +Ojú yín yóo rí ọba ninu ọlá ńlá rẹ̀;ẹ óo fojú yín rí ilẹ̀ tí ó lọ salalu. +Ẹ óo máa ronú ìnira tí ẹ ti ní pé:“Níbo ni akọ̀wé wà?Níbo ni ẹni tí ń gba owó orí wà?Níbo sì ni ẹni tí ń ka ilé ìṣọ́ wà?” +Ẹ kò ní rí àwọn aláfojúdi náà mọ́,àwọn tí wọn ń fọ èdè tí kò ní ìtumọ̀ si yín,tí wọn ń kólòlò ní èdè tí ẹ kò gbọ́. +Ṣàánú wa OLUWA,ìwọ ni a dúró tí à ń wò.Máa ràn wá lọ́wọ́ lojoojumọ,sì máa jẹ́ olùgbàlà wa nígbà ìṣòro. +Ẹ wo Sioni, ìlú tí a yà sọ́tọ̀ fún àjọ̀dún.Ẹ óo fi ojú rí Jerusalẹmu, ibùgbé alaafia, tí àgọ́ rẹ̀ kò ní ṣídìí,tí èèkàn tí a fi kàn án mọ́lẹ̀ kò ní hú laelae,bẹ́ẹ̀ ni okùn tí a fi so ó mọ́lẹ̀ kò ní já. +Ṣugbọn níbẹ̀ ni OLUWA, ninu ògo rẹ̀,yóo jẹ́ odò ńlá ati odò tí ń ṣàn fún wa;níbi tí ọkọ̀ ọlọ́pọ́n kò lè dé,ọkọ̀ ojú omi kò sì ní lè kọjá níbẹ̀. +Nítorí pé OLUWA ni onídàájọ́ wa,òun ni alákòóso wa;OLUWA ni ọba wa,òun ni yóo gbà wá là. +Okùn òpó-ọkọ̀ rẹ̀ ti tú,kò lè mú òpó-ọkọ̀ náà dáradára ní ipò rẹ̀ mọ́;kò sì lè gbé ìgbòkun dúró.A óo pín ọpọlọpọ ìkógun nígbà náà,kódà, àwọn arọ pàápàá yóo pín ninu rẹ̀. +Kò sí ará ìlú kan tí yóo sọ pé,“Ara mi kò yá.”A óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n. +Àwọn orílẹ̀-èdè sá nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo tí ó dàbí ti ààrá,wọ́n fọ́n ká nígbà tí o gbéra nílẹ̀. +A kó ìkógun jọ bí ìgbà tí tata bo oko,àwọn eniyan dà bo ìṣúra, bí ìgbà tí eṣú bo oko. +A gbé OLUWA ga!Nítorí pé ibi gíga ni ó ń gbé;yóo mú kí ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo kún Sioni. +Yóo mú kí ìdúróṣinṣin wà ní gbogbo àkókò rẹ̀.Yóo fún ọ ní ọpọlọpọ ìgbàlà, ati ọgbọ́n, ati ìmọ̀,ìbẹ̀rù OLUWA ni ìṣúra rẹ̀. +Ẹ wò ó, àwọn alágbára ń kígbe lóde,àwọn òjíṣẹ́ alaafia ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. +Òpópó ọ̀nà ṣófo,àwọn èrò kò rìn mọ́;wọ́n ń ba majẹmu jẹ́,wọn kò bìkítà fún ẹlẹ́rìí mọ́;wọ́n kò sì ka eniyan sí. +Ilẹ̀ ṣófo ó sì gbẹ,ìtìjú bá òkè Lẹbanoni,gbogbo ewéko orí rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.Ṣaroni dàbí aṣálẹ̀,igi igbó Baṣani ati ti òkè Kamẹli sì wọ́wé. +Ọlọrun Yóo Jẹ Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ níyà. +Ẹ súnmọ́ ibí, kí ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,ẹ tẹ́tí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin eniyan.Kí ilẹ̀ gbọ́ ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,kí ayé tẹ́tí sílẹ̀ pẹlu gbogbo nǹkan tí ń ti inú rẹ̀ jáde. +Yóo máa jó tọ̀sán-tòru, kò ní kú, yóo máa rú èéfín sókè títí lae.Yóo di aṣálẹ̀ láti ìrandíran,ẹnikẹ́ni kò ní gbabẹ̀ kọjá mọ́ títí lae. +Àṣá ati òòrẹ̀ ni yóo fi ibẹ̀ ṣe ilé,òwìwí ati ẹyẹ kannakánná ni yóo máa gbé ibẹ̀.OLUWA yóo ta okùn ìdàrúdàpọ̀ lé e lórí,yóo sì na ọ̀pá ìdàrúdàpọ̀ lé àwọn ìjòyè rẹ̀ lórí. +“Kò sí Ilẹ̀ Ọba Mọ́” ni a óo máa pè é.Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo parẹ́. +Ẹ̀gún yóo hù ninu ààfin rẹ̀,ẹ̀gún òṣùṣú ati ẹ̀gún ọ̀gàn yóo hù ninu àwọn ìlú olódi rẹ̀.Wọn yóo di ibùgbé fún àwọn ọ̀fàfà ati ẹyẹ ògòǹgò, +àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati ìkookò yóo jọ máa gbé ibẹ̀,àwọn ewúrẹ́ igbó yóo máa ké pe ara wọn.Iwin yóo rí ibi máa gbé,yóo sì rí ààyè máa sinmi níbẹ̀. +Òwìwí yóo pa ìtẹ́ sibẹ, tí yóo máa yé sí.Yóo pamọ, yóo ràdọ̀ bo àwọn ọmọ rẹ̀,yóo sì máa tọ́jú wọn níbẹ̀.Àwọn àṣá yóo péjọ sibẹ,olukuluku wọn, pẹlu ekeji rẹ̀. +Ẹ lọ wá inú ìwé OLUWA,kí ẹ ka ohun tí ó wà níbẹ̀.Kò sí ọ̀kan ninu àwọn wọnyi tí kò ní sí níbẹ̀,kò sí èyí tí kò ní ní ẹnìkejì.Nítorí OLUWA ni ó pàṣẹ bẹ́ẹ̀,ẹ̀mí rẹ̀ ni ó sì kó wọn jọ. +Ó ti ṣẹ́ gègé fún wọn, ó ti fi okùn wọ̀n ọ́n kalẹ̀ fún wọn.Àwọn ni wọn óo ni ín títí lae,wọn óo sì máa gbé ibẹ̀ láti ìrandíran. +Nítorí OLUWA ń bínú sí gbogbo orílẹ̀-èdè,inú rẹ̀ sì ń ru sí àwọn eniyan ibẹ̀.Ó ti fi wọ́n sílẹ̀ fún ìparun, ó sì ti fà wọ́n kalẹ̀ fún pípa. +A óo wọ́ òkú wọn jùnù,òkú wọn yóo máa rùn;ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn lórí àwọn òkè. +Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo gbọ̀n dànùa óo ká awọsanma bí ẹni ká ìwé.Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́bí ewé tií rẹ̀ sílẹ̀ lára ìtàkùn àjàrà,àní, bí ewé tií wọ́ dànù lórí igi ọ̀pọ̀tọ́. +Nítorí mo ti rẹkẹ idà mi lókè ọ̀run,yóo sọ̀kalẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ àwọn ará Edomu;yóo sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn tí mo fẹ́ parun. +OLUWA ní idà kan tí a tì bọ inú ẹ̀jẹ̀,a rì í sinu ọ̀rá,pẹlu ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ aguntan ati ti ewúrẹ́,ati ọ̀rá ara kíndìnrín àgbò.Nítorí pé OLUWA yóo rú ẹbọ ní Bosira,yóo sì pa ọpọlọpọ eniyan ní ilẹ̀ Edomu. +Àwọn mààlúù igbó yóo kú pẹlu wọn,bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ati àwọn akọ mààlúù ńlá.Ilẹ̀ wọn yóo kún fún ẹ̀jẹ̀,ọ̀rá eniyan yóo sì mú kí ilẹ̀ wọn lẹ́tù lójú. +Nítorí OLUWA ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ẹ̀san,ó ti ya ọdún kan sọ́tọ̀ tí yóo gbèjà Sioni. +Àwọn odò ilẹ̀ Edomu yóo di ọ̀dà,erùpẹ̀ rẹ̀ yóo di imí ọjọ́;ilẹ̀ Edomu yóo di ọ̀dà tí ń jó bùlàbùlà. +Ọ̀nà Ìwà Mímọ́. +Inú aṣálẹ̀ ati ilẹ̀ gbígbẹ yóo dùn,aṣálẹ̀ yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo rúwé, yóo sì tanná. +Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada,wọn óo wá sí Sioni pẹlu orin,ayọ̀ ayérayé yóo kún inú wọn.Wọn óo rí ayọ̀ ati ìdùnnú gbàìbànújẹ́ ati òṣé yóo sá kúrò níbẹ̀. +Nítòótọ́ yóo tanná bí òdòdó,yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo sì kọrin.Ògo Lẹbanoni yóo di tìrẹati iyì Kamẹli ati ti Ṣaroni.Wọn óo rí ògo OLUWA,wọn óo rí ọlá ńlá Ọlọrun wa. +Ẹ gbé ọwọ́ tí kò lágbára ró. Ẹ fún orúnkún tí kò lágbára ní okun. +Ẹ sọ fún àwọn tí àyà wọn ń já pé:“Ẹ ṣe ara gírí, ẹ má bẹ̀rù.Ẹ wò ó! Ọlọrun yín óo wá pẹlu ẹ̀san,ó ń bọ̀ wá gbẹ̀san gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun;ó ń bọ̀ wá gbà yín là.” +Ojú afọ́jú yóo là nígbà náà,etí adití yóo sì ṣí; +arọ yóo máa fò bí ìgalà, odi yóo sì máa kọ orin ayọ̀.Nítorí odò ńlá yóo ṣàn jáde ninu aginjùàwọn odò kéékèèké yóo máa ṣàn ninu aṣálẹ̀. +Ilẹ̀ iyanrìn gbígbóná yóo di adágún omiilẹ̀ gbígbẹ yóo di orísun omi,ibi tí ọ̀fàfà fi ṣe ilé tẹ́lẹ̀ yóo di àbàtà,èèsún ati ìyè yóo máa dàgbà níbẹ̀. +Òpópónà kan yóo wà níbẹ̀,a óo máa pè é ní Ọ̀nà Ìwà Mímọ́;nǹkan aláìmọ́ kan kò ní gba ibẹ̀ kọjá,àwọn aláìgbọ́n kò sì ní dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀. +Kò ní sí kinniun níbẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ẹranko burúkú kankan kò ní gba ibẹ̀.A kò ní rí wọn níbẹ̀,àwọn tí a ti rà pada ni yóo gba ibẹ̀. +Àwọn Ará Asiria Halẹ̀ mọ́ Jerusalẹmu. +Ní ọdún kẹrinla tí Ọba Hesekaya jọba, Senakeribu, ọba Asiria gbógun ti gbogbo ìlú olódi Juda, ó sì kó wọn. +Ẹ bi í pé, ṣé kò mọ̀ pé wíwá tí mo wá láti gbógun ti ìlú yìí ati láti pa á run kò ṣẹ̀yìn OLUWA? OLUWA ni ó sọ fún mi pé kí n lọ gbógun ti ilẹ̀ yìí, kí n sì pa á run.” +Nígbà náà ni Eliakimu ati Ṣebina ati Joa sọ fún Rabuṣake pé, “Jọ̀wọ́, èdè Aramaiki ni kí o fi bá wa sọ̀rọ̀, nítorí pé àwa náà gbọ́ Aramaiki. Má fi èdè Juda bá wa sọ̀rọ̀ kí àwọn ará wa tí ó wà lórí odi má baà gbọ́.” +Ṣugbọn Rabuṣake dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò pé ẹ̀yin ati oluwa yín nìkan ni oluwa mi rán mi pé kí n jíṣẹ́ yìí fún ni? Ṣé kò yẹ kí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n jókòó lórí odi ìlú yìí fetí wọn gbọ́ pé, ati àwọn ati ẹ̀yin, ẹ ti gbé, ẹ o máa jẹ ìgbọ̀nsẹ̀ ara yín, ẹ óo sì máa mu ìtọ̀ yín?” +Rabuṣake bá dìde dúró, ó sì kígbe ní èdè Juda, ó ní, “Ẹ gbọ́ ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria wí: +Ọba ní kí ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekaya tàn yín jẹ, nítorí kò ní le gbà yín là. +Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekaya mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, kí ó máa wí fún yín pé, ‘Dájúdájú OLUWA yóo gbà wá, ọba Asiria kò ní fi ogun kó ìlú yìí.’ +“Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ Hesekaya; nítorí ọba Asiria ní kí ẹ bá òun ṣe àdéhùn alaafia kí ẹ jáde tọ òun wá. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, olukuluku yín ni yóo máa jẹ èso àjàrà ati èso ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, olukuluku yín yóo sì máa mu omi ninu kànga rẹ̀; +títí òun óo fi wá mú yín lọ sí ilẹ̀ mìíràn tí ó dàbí ilẹ̀ yín, ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati ọtí, tí oúnjẹ ati ọgbà àjàrà ti pọ̀. +Ẹ ṣọ́ra kí Hesekaya má baà fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣì yín lọ́nà, kí ó máa sọ pé, ‘OLUWA yóo gbà wá.’ Ṣé ọ̀kankan ninu àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ti gba ilẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ Ọba Asiria rí? +Àwọn oriṣa Hamati ati Aripadi dà? Níbo ni àwọn oriṣa Sefafaimu wà? Ṣé wọn gba àwọn ará Samaria kalẹ̀ lọ́wọ́ mi? +Ọba Asiria rán Rabuṣake (olórí ogun rẹ̀), pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun; láti Lakiṣi sí ọba Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọn dé ibi tí omi tí ń ṣàn wọ ìlú láti orí òkè tí ó wà ní ọ̀nà pápá alágbàfọ̀, wọ́n dúró níbẹ̀. +Èwo ninu àwọn oriṣa ilẹ̀ wọnyi ni ó gba ilẹ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́wọ́ mi, tí ẹ fi rò pé OLUWA yóo gba Jerusalẹmu kalẹ̀ lọ́wọ́ mi?” +Gbogbo wọn dákẹ́, kò sí ẹnìkan tí ó sọ nǹkankan nítorí ọba ti pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dá a lóhùn. +Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó jẹ́ alákòóso ààfin ati Ṣebina, akọ̀wé ilé ẹjọ́, ati Joa, ọmọ Asafu, akọ̀wé ààfin wá sọ́dọ̀ Hesekaya pẹlu àwọn ti aṣọ wọn tí wọ́n ti fàya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, wọ́n sì sọ ohun tí Rabuṣake wí fún un. +Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó jẹ́ alákòóso ààfin jáde lọ bá wọn pẹlu Ṣebina, akọ̀wé ilé ẹjọ́, ati Joa ọmọ Asafu, akọ̀wé ààfin. +Rabuṣake bá sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún Hesekaya pé ọba ńlá Asiria ní kí ló gbójú lé rí? +Ó ní ṣé Hesekaya rò pé ọ̀rọ̀ ẹnu ni ọgbọ́n ati agbára tí wọ́n fi ń jagun ni; àbí ta ló gbójú lé tí ó fi ń ṣàìgbọràn sí òun? +Ó ní Ijipti tí Hesekaya gbára lé dàbí kí eniyan fi ìyè ṣe ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀, ìyè tí yóo dá, tí yóo sì gún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbára lé e lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ijipti jẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bá gbára lé e. +“Ó ní bí Hesekaya bá sì sọ fún òun pé, OLUWA Ọlọrun àwọn ni àwọn gbójú lé, òun óo bi í pé, ṣé kì í ṣe ojúbọ OLUWA náà ati àwọn pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀ ni Hesekaya wó lulẹ̀ nígbà tí ó sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu pé, ẹyọ pẹpẹ kan ni kí wọ́n ti máa sin OLUWA?” +Rabuṣake ní, “Mo fẹ́ kí Hesekaya bá oluwa mi, ọba Asiria, ṣe pàṣípààrọ̀ kan, n óo fún un ní ẹgbaa ẹṣin bí ó bá lè rí eniyan tó tí ó lè gùn wọ́n. +Báwo ni ó ṣe lè lé ẹni tí ó kéré jù ninu àwọn olórí-ogun oluwa mi pada sẹ́yìn, nígbà tí ó jẹ́ pé Ijipti ni ó gbójú lé pé wọn óo fún un ní kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin? +Ọba Bèèrè Ìmọ̀ràn lọ́wọ́ Aisaya. +Nígbà tí Hesekaya ọba gbọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì wọ inú ilé OLUWA lọ. +“Ẹ sọ fún Hesekaya ọba Juda pé kí ó má jẹ́ kí Ọlọrun rẹ̀ tí ó gbójú lé ṣì í lọ́nà kí ó sọ pé ọba Asiria kò ní fi ogun kó Jerusalẹmu. +Ṣebí Hesekaya ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Asiria ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, tí wọ́n pa wọ́n run patapata. Ṣé Hesekaya rò pé a óo gba òun là ni? +Ṣé àwọn oriṣa orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun gbà wọ́n sílẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Gosani ati Harani, Resefu ati àwọn ará Edẹni tí ń gbé Telasari? +Ọba Hamati dà? Ọba Aripadi ńkọ́? Níbo ni ọba ìlú Sefafaimu ati ọba Hena ati ọba Ifa wà?” +Hesekaya gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn ikọ̀ ọba Asiria, ó kà á. Nígbà tí ó kà á tán, ó gbéra, ó lọ sí ilé OLUWA, ó bá tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA, +Hesekaya bá gbadura sí OLUWA, ó ní: +“Ìwọ OLUWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israẹli, ìwọ tí ìtẹ́ rẹ wà lórí àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun gbogbo ìjọba ayé, ìwọ ni ó sì dá ọ̀run ati ayé. +Dẹtí sílẹ̀ OLUWA, kí o gbọ́. La ojú rẹ, OLUWA, kí o máa wo nǹkan. Gbọ́ irú iṣẹ́ tí Senakeribu rán tí ó ń fi ìwọ Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà. +Lóòótọ́ ni, OLUWA, pé àwọn ọba Asiria ti pa gbogbo orílẹ̀-èdè run tàwọn ti ilẹ̀ wọn, +ati pé wọ́n ju oriṣa wọn sinu iná, nítorí pé wọn kì í ṣe Ọlọrun. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n, tí wọ́n fi igi ati òkúta ṣe, nítorí náà ni wọ́n ṣe lè pa wọ́n run. +Ó rán Eliakimu tí ń ṣàkóso ààfin, ati Ṣebina akọ̀wé ilé ẹjọ́ ati àwọn àgbààgbà alufaa, wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, wọ́n lọ sọ́dọ̀ wolii Aisaya, ọmọ Amosi. +Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ nìkan ni OLUWA.” +Aisaya ọmọ Amosi bá ranṣẹ sí Hesekaya, pé OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí pé Hesekaya ti gbadura sí òun nípa Senakeribu ọba Asiria, +ohun tí OLUWA sọ nípa rẹ̀ ni pé:“Sioni bu ẹnu àtẹ́ lù ọ́, Senakeribu,ó fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà,Jerusalẹmu ń yọ ṣùtì sí ọ. +Ta ni ò ń sọ̀rọ̀ aṣa sí, tí ò ń fí ń ṣe ẹlẹ́yà?Ta ni ò ń ṣíjú wò pẹlu ìgbéraga?Ṣé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni o ṣe irú èyí sí? +O rán àwọn iranṣẹ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà,o ní,‘Mo ti fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi gun orí àwọn òkè gíga lọ,mo dé góńgó orí òkè Lẹbanoni.Mo ti gé àwọn igi kedari rẹ̀ tí ó ga jùlọ lulẹ̀,ati àwọn ààyò igi firi rẹ̀.Mo ti dé ibi tí ó ga jùlọ ní ilẹ̀ rẹ̀,ati igbó rẹ̀ tí ó dí jùlọ. +Mo gbẹ́ kànga mo sì mu omi ninu wọn.Mo ti fi ẹsẹ̀ mi tẹ gbogbo omi odò kéékèèké ilẹ̀ Ijipti ní àtẹ̀gbẹ.’ +“Ṣé o kò tíì gbọ́ pé láti ìgbà pípẹ́,ni mo ti pinnu ohun tí mò ń mú ṣẹ nisinsinyii?Láti ayébáyé ni mo ti ṣètò rẹ̀,pé kí o wó ìlú olódi palẹ̀,kí ó di òkítì àlàpà. +Kí àwọn eniyan tí ń gbé inú wọnmá ní agbára mọ́,kí wọ́n wà ninu ìdààmú ati ìpayà.Kí wọ́n dàbí ewé inú okoati bíi koríko tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ hùbí koríko tí ó hù lórí òrùlé,tíí gbẹ kí ó tó dàgbà. +“Mo mọ ìjókòó rẹ.Mo mọ ìjáde ati ìwọlé rẹ,ati inú tí ò ń bá mi bí. +Nítorí pé ò ń bá mi bínú,mo sì ti gbọ́ nípa ìwà ìgbéraga rẹ,n óo sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní imú,n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ ni ẹnu,n óo sì dá ọ pada sí ọ̀nà tí o gbà wá. +Wọ́n jíṣẹ́ fún un, wọ́n ní, “Hesekaya ní kí á sọ fún ọ pé: ‘Ọjọ́ ìṣòro ni ọjọ́ òní, ọjọ́ ìyà, ati ọjọ́ ẹ̀sín. Ọmọ ń mú aboyún, ó dé orí ìkúnlẹ̀, ṣugbọn kò sí agbára láti bíi. +“Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nìyí Hesekaya: Ní ọdún yìí, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ. Ní ọdún tí ń bọ̀ pẹlu, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ bákan náà. Ní ọdún kẹta, ẹ gbin nǹkan ọ̀gbìn, kí ẹ sì kórè rẹ̀, ẹ ṣe ọgbà àjàrà kí ẹ sì máa jẹ èso inú rẹ̀. +Àwọn ọmọ Juda tí ó bá ṣẹ́kù yóo fi gbòǹgbò múlẹ̀, wọn óo sì so èso. +Àwọn eniyan yóo ṣẹ́kù tí yóo wá láti Jerusalẹmu àwọn tí wọn yóo sá àsálà yóo wá láti orí òkè Sioni. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí. +“Nítorí náà, ohun tí OLUWA wí nípa ọba Asiria ni pé, ‘Kò ní wọ inú ìlú yìí, kò sì ní ta ọfà sí i. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò ní kó apata wọ inú rẹ̀. Wọn kò sì ní dó tì í. +Ọ̀nà tí ọba Asiria gbà wá ni yóo gbà pada lọ, kò ní fi ẹsẹ̀ kan inú ìlú yìí. +N óo dáàbò bo ìlú yìí, n óo sì gbà á sílẹ̀ nítorí tèmi ati nítorí Dafidi iranṣẹ mi.’ ” +Angẹli OLUWA bá lọ sí ibùdó àwọn ọmọ ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an ó lé ẹgbẹẹdọgbọn (185,000) ninu wọn. Nígbà tí wọn jí ní àfẹ̀mọ́júmọ́ òkú kún ilẹ̀ lọ kítikìti. +Senakeribu ọba Asiria bá pada sílé, ó ń lọ gbé ìlú Ninefe. +Ní ọjọ́ kan, ó lọ bọ Nisiroku, oriṣa rẹ̀, àwọn meji ninu àwọn ọmọ rẹ̀: Adirameleki ati Ṣareseri, sì fi idà gún un pa, wọ́n bá sá lọ sí ilẹ̀ Ararati. Esaradoni ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀. +Ó ṣeéṣe kí OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbọ́ iṣẹ́ tí ọba Asiria rán Rabuṣake, iranṣẹ rẹ̀, pé kí ó wá fi Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà, kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀! Nítorí náà gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè kí o gbadura fún àwọn eniyan tí ó kù.’ ” +Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Hesekaya ọba jíṣẹ́ fún Aisaya, +Aisaya dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wí fún oluwa yín pé OLUWA ní:‘Má bẹ̀rù nítorí ọ̀rọ̀ tí o gbọ́tí iranṣẹ ọba Asiria sọ tí ó ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà. +Ìwọ máa wò ó, n óo fi ẹ̀mí kan sí inú rẹ̀,yóo gbọ́ ìròyìn èké kan,yóo sì pada lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.Nígbà tí ó bá dé ilén óo jẹ́ kí wọ́n fi idà pa á.’ ” +Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi, nítorí náà, ó lọ bá a níbi tí ó ti ń bá àwọn ará Libina jagun. +Ibẹ̀ ni àwọn kan ti ròyìn fún ọba Asiria pé, Tirihaka ọba Etiopia ń bọ̀ wá gbógun tì í. Nígbà tí ó gbọ́, ó rán ikọ̀ lọ bá Hesekaya, ó ní: +Àìsàn Hesekaya ati Ìmúláradá Rẹ̀. +Ní àkókò náà, Hesekaya ṣàìsàn, àìsàn náà pọ̀; ó fẹ́rẹ̀ kú. Aisaya wolii, ọmọ Amosi tọ̀ ọ́ wá ní ọjọ́ kan, ó wí fún un pé: “OLUWA ní kí n sọ fún ọ pé kí o ṣe ètò ilé rẹ, nítorí pé o óo kú ni, o kò ní yè.” +Mo ti rò pé n óo kú lọ́jọ́ àìpé,ati pé a óo sé mi mọ́ inú ibojì,níbẹ̀ ni n óo sì ti lo ìyókù ọjọ́ ayé mi. +Mo rò pé n kò ní tún fojú kan OLUWA mọ́ ní ilẹ̀ alààyè,ati pé n kò ní sí láàyè mọ́láti tún fi ojú mi kan ẹnikẹ́ni. +A tú àgọ́ mi palẹ̀ bí àgọ́ darandaran,a sì ká a lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.Mo ká ayé mi bí aṣọ tí wọn ń hun.Ó sì gé mi kúrò bí aṣọ tí wọ́n gé kúrò lórí òfì.Mo ti kọ́ rò pé tọ̀sán-tòru ni ìwọ OLUWA ń fi òpin sí ayé mi. +Mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́ títí ilẹ̀ fi mọ́ó fọ́ gbogbo egungun mi bí kinniun ti máa ń fọ́ egungun.Tọ̀sán-tòru mo rò pé Ọlọrun ń fi òpin sí ayé mi ni. +Ọkàn mi ń ṣe hílàhílo bí ẹyẹ aláàpáǹdẹ̀dẹ̀ ati ẹyẹ àkọ̀,mò ń ké igbe arò bí àdàbà.Mo wòkè títí ojú ń ro mí,ara ń ní mí, OLUWA, nítorí náà ṣe ààbò mi. +Ṣugbọn kí ni mo lè sọ?Nítorí pé ó ti bá mi sọ̀rọ̀,òun fúnrarẹ̀ ni ó sì ṣe éOorun kò kùn mí nítorí pé ọkàn mi bàjẹ́. +OLUWA, nǹkan wọnyi ni ó mú eniyan wà láàyè,ninu gbogbo rẹ̀ èmi náà yóo wà láàyè.Áà, jọ̀wọ́ wò mí sàn, kí o mú mi wà láàyè. +Nítorí ìlera mi ni mo ṣe ní ìbànújẹ́ lọpọlọpọ;ìwọ ni o dì mí mú,tí n kò fi jìn sinu kòtò ìparun,nítorí o ti sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi di ohun ìgbàgbé. +Ibojì kò lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ikú kò lè yìn ọ́;kò sí ìrètí mọ́ fún àwọn tí wọ́n ti lọ sinu isà òkú,wọn kò lè gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ mọ́. +Alààyè, àní alààyè, ni ó lè máa yìn ọ́bí mo ti yìn ọ́ lónìí.Baba a máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, nípa òdodo rẹ. +Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó gbadura sí OLUWA, +OLUWA yóo gbà mí là,a óo fi àwọn ohun èlò orin olókùn kọrin ninu ilé OLUWA,ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. +Aisaya bá sọ fún Hesekaya pé kí wọn bá a wá èso ọ̀pọ̀tọ́ kí wọn lọ̀ ọ́, kí wọn fi lé ojú oówo tí ó mú un, kí ó lè gbádùn. +Hesekaya bá bèèrè pé, kí ni àmì tí òun óo fi mọ̀ pé òun óo tún fi ẹsẹ̀ òun tẹ ilé Olúwa? +ó ní, “OLUWA, dákun, mo bẹ̀ ọ́ ni, ranti bí mo ti ṣe fi tọkàntọkàn rìn níwájú rẹ pẹlu òtítọ́ inú, tí mo sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ.” Hesekaya bá sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. +OLUWA bá sọ fún Aisaya pé +kí ó lọ sọ fún Hesekaya pé, òun, OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀. Oun ti rí omijé rẹ̀, òun óo sì fi ọdún mẹẹdogun kún ọjọ́ ayé rẹ̀. +OLUWA ní òun óo gba Hesekaya lọ́wọ́ ọba Asiria, òun óo gbèjà ìlú Jerusalẹmu, òun óo sì dáàbò bò ó. +Aisaya ní, àmì tí OLUWA fún Hesekaya tí yóo mú kí ó dá a lójú pé òun OLUWA yóo ṣe ohun tí òun ṣèlérí nìyí: +Òun óo m�� kí òjìji oòrùn ìrọ̀lẹ́ pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi. Oòrùn bá yí pada nítòótọ́, òjìji sì pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀. +Orin tí Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nígbà tí ó ṣàìsàn tí Ọlọrun sì wò ó sàn nìyí: +Ọba Babiloni kọ ìwé kí Hesekaya. +Ní àkókò náà Merodaki Baladani ọmọ Baladani, ọba Babiloni, fi ìwé ati ẹ̀bùn rán àwọn ikọ̀ kan sí Hesekaya, nítorí ó gbọ́ pé ara rẹ̀ kò ti dá tẹ́lẹ̀ ṣugbọn ara rẹ̀ ti wá le. +Hesekaya gbà wọ́n lálejò, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà ninu ilé ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n, fadaka ati wúrà, àwọn nǹkan olóòórùn dídùn ati òróró olówó iyebíye, ilé ìkó nǹkan ìjà ogun sí, ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ilé ìṣúra. Kò sí nǹkan tí ó wà ní ìpamọ́ ní ààfin Hesekaya ní ilé rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n. +Lẹ́yìn náà Aisaya wolii tọ Hesekaya ọba lọ, ó bi í pé, “Kí ni àwọn ọkunrin wọnyi wí, láti ibo ni wọ́n sì ti wá sọ́dọ̀ rẹ?” Hesekaya dáhùn, ó ní, “Láti ilẹ̀ òkèèrè, ní Babiloni ni wọ́n ti wá.” +Aisaya tún bi í pé, “Kí ni wọ́n rí láàfin rẹ?” Hesekaya dáhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tó wà láàfin ni wọ́n rí. Kò sí ohun tí ó wà ní ilé ìṣúra mi tí n kò fihàn wọ́n.” +Aisaya bá sọ fún Hesekaya, pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun wí: +Ó ní, ‘Ọjọ́ ń bọ̀ tí a óo ru gbogbo ohun tí ó wà láàfin rẹ lọ sí Babiloni, ati gbogbo ìṣúra tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní. Kò ní ku nǹkankan.’ OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +‘A óo kó ninu àwọn ọmọ bíbí inú rẹ lọ, a óo sì fi wọ́n ṣe ìwẹ̀fà láàfin ọba Babiloni.’ ” +Hesekaya dá Aisaya lóhùn, ó ní, “Ohun rere ni OLUWA sọ.” Ó sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó rò pé alaafia ati ìfọ̀kànbalẹ̀ yóo wà ní àkókò tòun. +A óo Tún Jerusalẹmu Kọ́. +Tí ó bá di ìgbà náà, obinrin meje yóo rọ̀ mọ́ ọkunrin kan ṣoṣo, wọn óo máa bẹ̀ ẹ́ pé, “A óo máa bọ́ ara wa, a óo sì máa dá aṣọ sí ara wa lọ́rùn. Ṣá máa jẹ́ ọkọ wa, kí á máa jẹ́ orúkọ rẹ; kí o mú ìtìjú kúrò lọ́rọ̀ wa.” +Tí ó bá di ìgbà náà, ẹ̀ka igi OLUWA yóo di ohun ẹwà ati iyì. Èso ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ògo ati àmúyangàn fún àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá kù. +Eniyan mímọ́ ni a óo máa pe àwọn tí wọ́n bá kù ní Sioni, àní, àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Jerusalẹmu; gbogbo àwọn tí a bá kọ orúkọ wọn sílẹ̀ pé wọ́n wà láàyè ní Jerusalẹmu. +Nígbà tí OLUWA bá ti fọ èérí Jerusalẹmu dànù, tí ó sì jó o níná tí ó sì mú ẹ̀bi ìpànìyàn kúrò níbẹ̀, nípa pé kí wọn máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́, +ní ọ̀sán, yóo mú kí ìkùukùu bo gbogbo òkè Sioni ati àwọn tí ó ń péjọ níbẹ̀; ní alẹ́, yóo sì fi èéfín ati ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ bò wọ́n. Ògo OLUWA yóo bò wọ́n bí àtíbàbà ati ìbòrí. +Yóo dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ oòrùn lọ́sàn-án, yóo jẹ́ ibi ìsásí ati ààbò fún wọn lọ́wọ́ ìjì ati òjò. +Ọ̀rọ̀ Ìtùnú fún Àwọn Ọmọ Israẹli. +Ọlọrun yín ní, “Ẹ tù wọ́n ninu,ẹ tu àwọn eniyan mi ninu. +Ẹ wò ó! OLUWA Ọlọrun ń bọ̀ pẹlu agbára ipá rẹ̀ ni yóo fi máa ṣe àkóso.Ẹ wò ó! Èrè rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀. +Yóo bọ́ agbo ẹran bí olùṣọ́-aguntan. Yóo kó àwọn ọ̀dọ́ aguntan jọ sí apá rẹ̀,yóo gbé wọn mọ́ àyà rẹ̀.Yóo sì máa fi sùúrù da àwọn tí wọn lọ́mọ lẹ́yìn láàrin wọn. +Ta ló lè fi kòtò ọwọ́ wọn omi òkun?Ta ló lè fìka wọn ojú ọ̀run,Kí ó kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayésinu òṣùnwọ̀n?Ta ló lè gbé àwọn òkè ńlá ati àwọn kéékèèké sórí ìwọ̀n? +Ta ló darí Ẹ̀mí OLUWA, ta ló sì tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀? +Ọwọ́ ta ni OLUWA ti gba ìmọ̀ràn tí ó fi ní òye,ta ló kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń dájọ́ ẹ̀tọ́,tí ó kọ́ ọ ní ìmọ̀,tí ó sì fi ọ̀nà òye hàn án? +Wò ó, àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ìkán omi kan ninu garawa omi, ati bí ẹyọ eruku kan lórí òṣùnwọ̀n.Ẹ wò ó, ó mú àwọn erékùṣù lọ́wọ́ bí àtíkè. +Gbogbo igi igbó Lẹbanoni kò tó fún iná ẹbọ,bẹ́ẹ̀ ni ẹranko ibẹ̀ kò tó fún ẹbọ sísun. +Gbogbo orílẹ̀-èdè kò tó nǹkan níwájú rẹ̀,wọn kò jámọ́ nǹkan lójú rẹ̀, òfo ni wọ́n. +Ta ni ẹ lè fi Ọlọrun wé,tabi kí ni ẹ lè fi ṣe àkàwé rẹ̀? +Ṣé oriṣa ni! Tí oníṣẹ́ ọwọ́ ṣe; tí alágbẹ̀dẹ wúrà yọ́ wúrà bòtí ó sì fi fadaka ṣe ẹ̀wọ̀n fún? +Ẹ bá Jerusalẹmu sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ẹ ké sí i pé, ogun jíjà rẹ̀ ti parí,a ti dárí àìṣedéédé rẹ̀ jì í.OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà ní ìlọ́po meji nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” +Ẹni tí ó bá talaka, tí kò lágbára nǹkan ìrúbọ, a wá igi tí kò lè rà, tí kò sì lè ju;a wá agbẹ́gilére tí ó mọṣẹ́,láti bá a gbẹ́ ère tí kò lè paradà. +Ṣé ẹ kò tíì mọ̀?Ẹ kò sì tíì gbọ́?Ṣé wọn kò sọ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀,kò sì ye yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, pé: +Òun ni ó jókòó lókè àyíká ayé,àwọn eniyan inú rẹ̀ sì dàbí tata lójú rẹ̀.Òun ni ó ta awọsanma bí aṣọ títa,ó sì ta á bí àgọ́, ó ń gbébẹ̀. +Ẹni tí ó sọ àwọn ọba di ẹni ilẹ̀,ó sọ àwọn olóyè ayé di asán. +Wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì gbìn wọ́n,wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì ta gbòǹgbò wọlẹ̀;nígbà tí ó fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n,tí wọ́n fi rọ bí ewéko,tí ìjì sì gbé wọn lọ bí àgékù koríko. +Ta ni ẹ óo wá fi mí wé,tí n óo sì dàbí rẹ̀?Èmi Ẹni Mímọ́ ni mo bèèrè bẹ́ẹ̀. +Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo ojú ọ̀run, ta ni ó dá àwọn nǹkan tí ẹ rí wọnyi?Ẹni tí ó kó àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run bí ọmọ ogun,tí ó ń pè wọ́n jáde lọ́kọ̀ọ̀kan,tí ó sì mọ olukuluku mọ́ orúkọ rẹ̀.Nítorí bí ipá rẹ̀ ti tó,ati bí agbára rẹ̀ ti pọ̀ tó,ẹyọ ọ̀kan ninu wọn kò di àwátì. +Kí ló dé, Jakọbu, tí o fi ń rojọ́?Kí ló ṣe ọ́, Israẹli, tí o fi ń sọ pé,“OLUWA kò mọ ohun tí ń ṣe mí,Ọlọrun kò sì bìkítà nípa ẹ̀tọ́ mi.” +Ṣé o kò tíì mọ̀,o kò sì tíì gbọ́pé Ọlọrun ayérayé ni OLUWA,Ẹlẹ́dàá gbogbo ayé.Kì í rẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a.Àwámárìídìí ni òye rẹ̀. +A máa fún aláàárẹ̀ ní okun.A sì máa fún ẹni tí kò lágbára ní agbára. +Ẹ gbọ́ ohùn akéde kan tí ń wí pé, “Ẹ tún ọ̀nà OLUWA ṣe ninu aginjù,ẹ la òpópónà títọ́ fún Ọlọrun wa ninu aṣálẹ̀. +Yóo rẹ àwọn ọ̀dọ́ pàápàá, agara óo sì dá wọn,àwọn ọdọmọkunrin yóo tilẹ̀ ṣubú lulẹ̀ patapata. +Ṣugbọn àwọn tí ó bá dúró de OLUWAyóo máa gba agbára kún agbára.Wọn óo máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì.Wọn óo máa sáré, agara kò ní dá wọn;wọn óo máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n. +Gbogbo àfonífojì ni a óo ru sókè,a óo sì sọ àwọn òkè ńlá ati òkè kéékèèké di pẹ̀tẹ́lẹ̀:Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ́ ni yóo di títọ́,ọ̀nà gbágun-gbàgun yóo sì di títẹ́jú. +Ògo OLUWA yóo farahàn, gbogbo eniyan yóo sì jọ fojú rí i.OLUWA ni ó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀.” +Mo gbọ́ ohùn kan tí ń wí pé, “Kígbe!”Mo bá bèèrè pé,“Igbe kí ni kí n ké?”Ó ní, “Kígbe pé, koríko ṣá ni gbogbo eniyan,gbogbo ẹwà sì dàbí òdòdó inú pápá. +Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú.Dájúdájú koríko ni eniyan. +Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀;ṣugbọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa dúró títí lae.” +Gun orí òkè gíga lọ, ìwọ Sioni,kí o máa kéde ìyìn rere.Gbé ohùn rẹ sókè pẹlu agbára Jerusalẹmu,ìwọ tí ò ń kéde ìyìn rereké sókè má ṣe bẹ̀rù;sọ fún àwọn ìlú Juda pé,“Ẹ wo Ọlọrun yín.” +Ọlọrun fún Israẹli ní Ìdánilójú. +“Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin erékùṣù,kí àwọn eniyan gba agbára kún agbára wọn,kí wọ́n súnmọ́ ìtòsí, kí wọ́n sọ tẹnu wọn,ẹ jẹ́ kí á pàdé ní ilé ẹjọ́. +Má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ,má fòyà, nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ.N óo fún ọ ní agbára, n óo sì ràn ọ́ lọ́wọ́;ọwọ́ ọ̀tún mi, ọwọ́ ìṣẹ́gun, ni n óo fi gbé ọ ró. +“Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́ runni n óo dójú tì, wọn óo sì dààmú.Àwọn tí ń bá ọ jà yóo di asán,wọn óo sì ṣègbé. +O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì,o kò ní rí wọn.Àwọn tí ó gbógun tì ọ́yóo di òfo patapata. +Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ,ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,èmi ni mo sọ fún ọ pékí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.” +Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán,ẹ̀yin ọmọ Israẹli,OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́.Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín. +Ó ní, “N óo ṣe yín bí ohun èlò ìpakà titun,tí ó mú, tí ó sì ní eyín,ẹ óo tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, ẹ óo rún wọn wómúwómú;ẹ óo sì sọ àwọn òkè kéékèèké di fùlùfúlù. +Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ,ìjì yóo sì fọ́n wọn ká.Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWAẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli. +“Nígbà tí àwọn talaka ati àwọn aláìní bá ń wá omi, tí omi kò sí,tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n, tí ọ̀nà ọ̀fun wọn gbẹ,èmi OLUWA yóo dá wọn lóhùn,èmi Ọlọrun Israẹli kò ní fi wọ́n sílẹ̀. +N óo ṣí odò lórí àwọn òkè,ati orísun láàrin àwọn àfonífojì;n óo sọ aṣálẹ̀ di adágún odò,ilẹ̀ gbígbẹ yóo sì di orísun omi. +N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀,pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi.N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀,n óo gbin igi firi ati pine papọ̀. +“Ta ló gbé ẹnìkan dìde ní ìhà ìlà oòrùn?Tí ó ń ṣẹgun ní ibikíbi tí ó bá fẹsẹ̀ tẹ̀?Ta ló fi àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́tí ó fi lè tẹ àwọn ọba mọ́lẹ̀?Idà rẹ̀ gé wọn bí eruku,ọfà rẹ̀ sì tú wọn ká bí àgékù koríko. +Kí àwọn eniyan lè rí i, kí wọn sì mọ̀,kí wọ́n rò ó wò, kí òye lè yé wọn papọ̀,pé ọwọ́ OLUWA ni ó ṣe èyí,Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀.” +OLUWA, Ọba Jakọbu, ní:“Ẹ̀yin oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ ro ẹjọ́ yín,kí ẹ mú ẹ̀rí tí ó dájú wá lórí ohun tí ẹ bá ní sọ. +Ẹ mú wọn wá,kí ẹ sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa;kí ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́ fún wa.Kí á lè gbé wọn yẹ̀wò;kí á lè mọ àyọrísí wọn,tabi kí ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún wa.” +OLUWA ní, “Ẹ sọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la fún wa,kí á lè mọ̀ pé oriṣa ni yín;ẹ ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú kan,kí á rí i, kí ẹ̀rù sì bà wá. +Ẹ wò ó! Òfo ni yín, òfo sì ni iṣẹ́ ọwọ́ yín,ẹni ìríra ni ẹni tí ó bá yàn yín. +Mo ti gbé ẹnìkan dìde láti ìhà àríwá,ó sì ti dé.Láti ìlà oòrùn ni yóo ti pe orúkọ mi;yóo máa gún àwọn ọba mọ́lẹ̀ bì ìgbà tí wọ́n gún nǹkan ninu odó,àní, bí ìgbà tí amọ̀kòkò bá ń gún amọ̀. +Ta ló kéde rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, kí á lè mọ̀,ta ló sọ nípa rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀kí á lè sọ pé, ‘Olóòótọ́ ni?’Kò sí ẹni tí ó sọ ọ́, kò sí ẹni tí ó kéde rẹ̀;ẹnìkankan kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. +Èmi OLUWA ni mo ti kọ́kọ́ sọ fún Sioni,tí mo sì ròyìn ayọ̀ náà fún Jerusalẹmu. +Nígbà tí mo wo ààrin àwọn wọnyi, kò sí olùdámọ̀ràn kan,tí ó lè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ní ìbéèrè. +Wò ó! Ìtànjẹ lásán ni gbogbo wọn,òfo ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn:Ẹ̀fúùfù lásán ni àwọn ère tí wọ́n gbẹ́.” +A máa lépa wọn, a sì máa kọjá wọn láìléwu,ní ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tẹ̀ rí. +Ta ló ṣe èyí?Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni?Tí ó pe ìran dé ìran láti ìbẹ̀rẹ̀?Èmi OLUWA ni, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn. +“Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù bà wọ́n,gbogbo òpin ayé gbọ̀n rìrì wọ́n ti súnmọ́ tòsí, wọ́n ti dé. +Olukuluku ń ran ẹnìkejì rẹ̀ lọ́wọ́,ó ń sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ṣara gírí.’ +Agbẹ́gilére ń gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjúẹni tí ń fi òòlù lu irin ń kí ẹni tí ń dán irin tí wọ́n ti rọ,Ó ń wí pé: ‘Òjé tí a fi jó o dára.’Wọ́n kàn án ní ìṣó,ó le dáradára, kò le mì. +“Ìwọ ní tìrẹ, Israẹli iranṣẹ mi, Jakọbu, ìwọ tí mo ti yàn,ọmọ bíbí inú Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi. +Ìwọ tí mo mú wá láti òpin ayé,tí mo pè láti ìkangun ayé tí ó jìnnà jùlọ,mo wí fún ọ pé, ‘Iranṣẹ mi ni ọ́,mo ti yàn ọ́, n kò ní ta ọ́ nù.’ +Iranṣẹ Ọlọrun. +OLUWA ní,“Wo iranṣẹ mi, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi, ẹni tí inú mi dùn sí.Mo ti jẹ́ kí ẹ̀mí mi bà lé e,yóo máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè. +Ẹ kọ orin tuntun sí OLUWA;ẹ kọ orin ìyìn rẹ̀ láti òpin ayé.Ẹ̀yin èrò inú ọkọ̀ lójú agbami òkun,ati gbogbo ohun tí ó wà ninu omi òkun;ati àwọn erékùṣù ati àwọn tí ń gbé inú wọn. +Kí aṣálẹ̀ ati àwọn ìlú inú rẹ̀ kọ orin ìyìn sókè,ati àwọn abúlé agbègbè Kedari;kí àwọn ará ìlú Sela kọrin ayọ̀,kí wọn máa kọrin lórí àwọn òkè. +Kí wọn fi ògo fún OLUWA,kí wọn kéde ìyìn rẹ̀ ní àwọn erékùṣù. +OLUWA yọ jáde lọ bí alágbára ọkunrin,ó ru ibinu rẹ̀ sókè bí ọkunrin ogun,ó kígbe, ó sì bú ramúramù.Ó fihàn pé alágbára ni òun níwájú àwọn ọ̀tá rẹ̀.OLUWA ní: +“Ó ti pẹ́ tí mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́,mo dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo mára dúró.Ṣugbọn nisinsinyii, n óo kígbe,bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́.N óo máa mí túpetúpe,n óo máa mí hẹlẹhẹlẹ. +N óo sọ àwọn òkè gíga ati àwọn kéékèèké di ilẹ̀,n óo mú kí gbogbo ewéko orí wọn gbẹ;n óo sọ àwọn odò di erékùṣù,n óo sì mú kí àwọn adágún omi gbẹ. +“N óo darí àwọn afọ́jú,n óo mú wọn gba ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí,n óo tọ́ wọn sọ́nà,ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí.N óo sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn,n óo sì sọ àwọn ibi tí ó rí pálapàla di títẹ́jú.N óo ṣe àwọn nn��kan,n kò sì ní kọ̀ wọ́n sílẹ̀. +A óo ká àwọn tí ó gbójú lé ère lọ́wọ́ kò,ojú yóo sì tì wọ́n patapataàwọn tí ń wí fún ère gbígbẹ́ pé:‘Ẹ̀yin ni Ọlọrun wa.’ ”OLUWA ní: +“Gbọ́, ìwọ adití,sì wò ó, ìwọ afọ́jú, kí o lè ríran. +Ta ni afọ́jú, bíkòṣe iranṣẹ mi?Ta sì ni adití, bíkòṣe ẹni tí mo rán níṣẹ́?Ta ni ó fọ́jú tó ẹni tí mo yà sọ́tọ̀,tabi ta ni ojú rẹ̀ fọ́ tó ti iranṣẹ OLUWA? +Kò ní kígbe, kò sì ní pariwo,kò ní jẹ́ kí á gbọ́ ohùn rẹ̀ ní ìta gbangba. +Ó ń wo ọpọlọpọ nǹkan, ṣugbọn kò ṣe akiyesi wọn.Etí rẹ̀ là sílẹ̀,ṣugbọn kò gbọ́ràn.” +Ó wu OLUWA láti gbé òfin rẹ̀ gaati láti ṣe é lógo nítorí òdodo rẹ̀. +Ṣugbọn a ti ja àwọn eniyan wọnyi lólè,a sì ti kó wọn lẹ́rù,a ti sé gbogbo wọn mọ́ inú ihò ilẹ̀,a sì ti fi wọ́n pamọ́ sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n.A fogun kó wọn, láìsí ẹni tí yóo gbà wọ́n sílẹ̀,a kó wọn lẹ́rú, láìsí ẹnikẹ́ni tí yóo sọ pé:“Ẹ dá wọn pada.” +Èwo ninu yín ló fetí sí èyí,tabi tí yóo farabalẹ̀ gbọ́ nítorí ẹ̀yìn ọ̀la? +Ta ló fa Jakọbu lé akónilẹ́rù lọ́wọ́,ta ló sì fa Israẹli lé àwọn ọlọ́ṣà lọ́wọ́?Ṣebí OLUWA tí a ti ṣẹ̀ ni,ẹni tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀;tí wọn kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́. +Nítorí náà ó jẹ́ kí wọ́n rí ibinu òun,ó sì fi agbára ogun rẹ̀ hàn wọ́n.Ó tanná ràn án lọ́tùn-ún lósì, sibẹ kò yé e;iná jó o, sibẹsibẹ kò fi ṣe àríkọ́gbọ́n. +Kò ní ṣẹ́ ọ̀pá ìyè tí ó tẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní pa iná fìtílà tí ń jò bẹ́lúbẹ́lú,yóo fi òtítọ́ dá ẹjọ́. +Kò ní kùnà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì, títí yóo fi fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ láyé.Àwọn erékùṣù ń retí òfin rẹ̀.” +Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ; ẹni tí ó dá ojú ọ̀run tí ó sì ta á bí aṣọ,tí ó tẹ ayé, ati àwọn ohun tí ń hù jáde láti inú rẹ̀;ẹni tí ó fi èémí sinu àwọn eniyan tí ń gbé orí ilẹ̀;tí ó sì fi ẹ̀mí fún àwọn tí ó ń rìn lórí rẹ̀. +Ó ní, “Èmi ni OLUWA, mo ti pè ọ́ ninu òdodo, mo ti di ọwọ́ rẹ mú,mo sì pa ọ́ mọ́.Mo ti fi ọ́ ṣe majẹmu fún aráyé,mo sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè; +kí o lè la ojú àwọn afọ́jú,kí o lè yọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kúrò ni àhámọ́,kí o lè yọ àwọn tí ó jókòó ninu òkùnkùn kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. +“Èmi ni OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni orúkọ mi;n kò ní fi ògo mi fún ẹlòmíràn,n kò sì ní fi ìyìn mi fún ère. +Wò ó! Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá,àwọn nǹkan tuntun ni mò ń kéde nisinsinyii.Kí wọn tó yọjú jáde rárá,ni mo ti sọ fún ọ nípa wọn.” +OLUWA Ṣe Ìlérí láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là. +Ṣugbọn nisinsinyii, Jakọbu,gbọ́ nǹkan tí OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ wí,Israẹli, gbọ́ ohun tí ẹni tí ó dá ọ sọ.Ó ní, “Má bẹ̀rù, nítorí mo ti rà ọ́ pada;mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ, èmi ni mo ni ọ́. +OLUWA ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,ẹ̀yin ni iranṣẹ mi tí mo yàn;kí ẹ lè mọ̀ mí, kí ẹ sì gbà mí gbọ́,kí ó sì ye yín pé, Èmi ni.A kò dá Ọlọrun kankan ṣáájú mi,òmíràn kò sì ní wáyé lẹ́yìn mi. +“Èmi ni OLUWA,kò sí olùgbàlà kan, yàtọ̀ sí mi. +Mo ti sọ̀rọ̀ ìṣípayá, mo ti gba eniyan là,mo sì ti kéde,nígbà tí kò sí Ọlọrun àjèjì láàrin yín;ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Èmi ni Ọlọrun,láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi ni.Kò sí ẹnìkan tí ó lè gba eniyan kalẹ̀ lọ́wọ́ mi:Ta ni le dínà ohun tí mo bá níí ṣe?” +OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùràpadà yín, ní,“N óo ranṣẹ sí Babiloni nítorí yín,n óo dá gbogbo ọ̀pá ìlẹ̀kùn ibodè,ariwo ẹ̀rín àwọn ará Kalidea yóo sì di ẹkún. +Èmi ni OLUWA, Ẹni Mímọ́ yín,Ẹlẹ́dàá Israẹli, Ọba yín.” +OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun,tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá; +ẹni tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin jáde, ogun, ati àwọn ọmọ-ogun;wọ́n dùbúlẹ̀ wọn kò lè dìde mọ́,wọ́n kú bí iná fìtílà. +ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́,kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá. +Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titunó ti yọ jáde nisinsinyii,àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀?N óo la ọ̀nà ninu aginjù,n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀. +Nígbà tí o bá ń la ibú omi kọjá,n óo wà pẹlu rẹ;nígbà tí o bá la odò ńlá kọjá,kò ní bò ọ́ mọ́lẹ̀,nígbà tí o bá ń kọjá ninu iná, kò ní jó ọ.Ahọ́n iná kò ní jó ọ run. +Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo,ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò;nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀,kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu: +Àwọn tí mo fọwọ́ mi dá fún ara mi,kí wọ́n lè kéde ògo mi. +“Sibẹsibẹ, ẹ kò ké pè mí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,ọ̀rọ̀ mi ti su yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. +Ẹ kò wá fi aguntan rúbọ sí mi,tabi kí ẹ wá fi ẹbọ rírú bu ọlá fún mi.N kò fi tipátipá mu yín rúbọ,bẹ́ẹ̀ ni n kò sọ pé dandan ni kí ẹ mú turari wá. +Ẹ kò fowó yín ra turari olóòórùn dídùn fún mi,tabi kí ẹ fi ọ̀rá ẹbọ yín tẹ́ mi lọ́rùn.Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ yín yọ mí lẹ́nu,ẹ sì ń dààmú mi pẹlu àìdára yín. +Èmi, èmi ni mo pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́,nítorí ti ara mi;n kò sì ní ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́. +“Ẹ rán mi létí ọ̀rọ̀ yín kí á jọ ṣàríyànjiyàn;ẹ ro ẹjọ́ tiyín,kí á lè da yín láre. +Baba ńlá yín àkọ́kọ́ ṣẹ̀,àwọn aṣiwaju yín náà sì ṣẹ̀ mí. +Nítorí náà mo sọ àwọn olórí ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,mo fi Jakọbu sílẹ̀ fún ìparun;mo sì sọ Israẹli di ẹni ẹ̀sín.” +Nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ,Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùgbàlà rẹ.Mo fi Ijipti, lélẹ̀, láti rà ọ́ pada,mo sì fi Etiopia ati Seba lélẹ̀ mo ti fi ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ. +Nítorí pé o ṣọ̀wọ́n lójú mi, o níyì, mo sì fẹ́ràn rẹ,mo fi àwọn eniyan rọ́pò rẹ;mo sì fi ẹ̀mí àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí rẹ. +Má bẹ̀rù nítorí mo wà pẹlu rẹ,n óo kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn,n óo sì ko yín jọ láti ìwọ̀ oòrùn. +N óo pàṣẹ fún ìhà àríwá pé,‘Dá wọn sílẹ̀.’N óo sọ fún ìhà gúsù pé,‘O kò gbọdọ̀ dá wọn dúró.’Kó àwọn ọmọ mi ọkunrin wá láti òkèèrè,sì kó àwọn ọmọ mi obinrin wá láti òpin ayé, +gbogbo àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè,àwọn tí mo dá fún ògo mi,àwọn tí mo fi ọwọ́ mi ṣẹ̀dá wọn.” +Ẹ mú àwọn eniyan mi jáde,àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí ojú wọn ti fọ́,wọ́n ní etí, ṣugbọn etí wọn ti di. +Jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè péjọ,kí àwọn eniyan àgbáyé parapọ̀.Èwo ninu wọn ni ó lè kéde irú àsọtẹ́lẹ̀ yìí,tí ó lè fi àwọn ohun àtijọ́ hàn wá;kí wọn pe ẹlẹ́rìí wọn wá, kí á lè mọ̀ pé ẹjọ́ wọn tọ́,kí àwọn ẹlòmíràn lè gbọ́, kì wọn sì jẹ́rìí pé, “Òtítọ́ ni.” +Ọlọrun kanṣoṣo ni OLUWA. +OLUWA ní:“Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu iranṣẹ miẹ̀yin ọmọ Israẹli, àyànfẹ́ mi. +Ta ló ṣe oriṣa, ta ló sì yá ère tí kò lérè? +Ojú yóo ti gbogbo wọn; eniyan sá ni wọ́n. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wọn pésẹ̀, kí wọ́n jáde wá. Ìpayà yóo bá wọn, ojú yóo sì ti gbogbo wọn papọ̀. +Alágbẹ̀dẹ a mú irin, a fi sinu iná, a máa fi ọmọ owú lù ú, a sì fi agbára rẹ̀ rọ ọ́ bí ó ti fẹ́ kí ó rí. Ebi a pa á, àárẹ̀ a sì mú un; kò ní mu omi, a sì máa rẹ̀ ẹ́. +Agbẹ́gilére a ta okùn sára igi, a fi ẹfun fa ìlà sí i, a fi ìwọ̀n wọ̀n ọ́n, a sì gbẹ́ ẹ bí eniyan: ẹwà rẹ̀ a dàbí ti eniyan, wọn a sì kọ́lé fún un. +Ó lè gé igi kedari lulẹ̀, tabi kí ó gbin igi Sipirẹsi, tabi igi Oaku, kí ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrin àwọn igi inú igbó. Ó sì lè gbin igi kedari kan, omi òjò a sì mú kí ó dàgbà. +Lẹ́yìn náà igi yìí di igi ìdáná: Eniyan óo gé ninu rẹ̀, yóo fi dáná yá; yóo gé ninu rẹ̀ yóo fi dáná oúnjẹ; yóo gé ninu rẹ̀, yóo fi gbẹ́ ère, yóo máa bọ ọ́. Eniyan á wá sọ igi lásán tí ó gbẹ́ di oriṣa, á sì máa foríbalẹ̀ fún un. +Yóo fi ìdajì rẹ̀ dáná, yóo fi se oúnjẹ, yóo fi se ẹran rẹ̀ pẹlu. Yóo jẹun, yóo jẹran, yóo yó; yóo tún yáná. Yóo ní, “Áà! Ooru mú mi nítorí mo rí iná yá.” +Yóo fi èyí tí ó kù gbẹ́ ère oriṣa rẹ̀, yóo máa foríbalẹ̀ fún un, yóo máa bọ ọ́, yóo máa gbadura sí i pé, “Gbà mí, nítorí ìwọ ni Ọlọrun mi.” +Wọn kò mọ nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn. Nǹkankan ti bò wọ́n lójú kí wọn má baà lè ríran; ó sì ti sé wọn lọ́kàn kí òye má baà yé wọn. +Kò sí ẹni tí ó ronú wò, tabi tí ó ní ìmọ̀ tabi òye, láti wí pé: “Ìdajì igi yìí ni mo fi dáná tí mo fi se oúnjẹ, tí mo sì fi se ẹran tí mo jẹ. Kí ló wá dé tí n óo ṣe fi ìyókù gbẹ́ ère kí n máa bọ ọ́? Ṣé ìtì igi lásán ló yẹ kí n máa foríbalẹ̀ fún, kí n máa bọ?” +Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ẹlẹ́dàá yín wí,ẹni tí ó ṣẹ̀dá yín láti inú oyún,tí yóo sì ràn yín lọ́wọ́:Ẹ má bẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,Jeṣuruni, ẹni tí mo yàn. +Kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń pe eérú ní oúnjẹ. Èrò ẹ̀tàn ti ṣì í lọ́nà, kò sì lè gba ara rẹ̀ kalẹ̀ tabi kí ó bi ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ irọ́ kọ́ ni ohun tí ó wà lọ́wọ́ mi yìí?” +Jakọbu, ranti àwọn nǹkan wọnyi,nítorí pé iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli.Èmi ni mo ṣẹ̀dá rẹ, iranṣẹ mi ni ọ́,n kò jẹ́ gbàgbé rẹ, Israẹli. +Mo ti ká àìdára rẹ kúrò bí awọsanma,mo ti gbá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ dànù bí ìkùukùu.Pada sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ pada. +Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLUWA ti ṣe é.Ẹ pariwo, ẹ̀yin ìsàlẹ̀ ilẹ̀.Ẹ kọrin, ẹ̀yin òkè ńlá, ìwọ igbó ati igi inú rẹ̀,nítorí OLUWA ti ra Jakọbu pada,yóo sì ṣe ara rẹ̀ lógo ní Israẹli. +Gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà rẹ wí,ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú oyún.Ó ní, “Èmi ni OLUWA, tí mo dá ohun gbogbo.Èmi nìkan ni mo tẹ́ ojú ọ̀run,tí mo sì dá ilẹ̀ ayé tẹ́, +èmi tí mo sọ àmì àwọn tí ń woṣẹ́ èké di asán, tí mo sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀.Mo yí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n pomo sì sọ ọgbọ́n wọn di òmùgọ̀. +Èmi tí mo jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ iranṣẹ mi,tí mo sì mú ìmọ̀ àwọn ikọ̀ mi ṣẹ,èmi tí mo wí fún Jerusalẹmu pé,‘Àwọn eniyan yóo máa gbé inú rẹ,’tí mo sì wí fún àwọn ìlú Juda pé,‘A óo tún odi yín mọ,n óo sì tún yín kọ́.’ +Èmi tí mo pàṣẹ fún agbami òkun pé, ‘Gbẹ!n óo mú kí àwọn odò rẹ gbẹ;’ +èmi tí mo sọ fún Kirusi pé: ‘Ìwọ ni ọba tí n óo yàn tí yóo mú gbogbo ìpinnu mi ṣẹ;’tí mo sọ fún Jerusalẹmu pé:‘A óo tún odi rẹ̀ mọ,’tí mo sì sọ fún Tẹmpili pé,‘A óo tún fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀.’ ” +“N óo tú omi sórí ilẹ̀ tí òùngbẹ ń gbẹn óo sì ṣe odò sórí ilẹ̀ gbígbẹ.N óo tú ẹ̀mí mi sórí àwọn ọmọ yín,n óo da ibukun mi sórí arọmọdọmọ yín, +wọn óo rúwé bíi koríko inú omi àní, bíi igi wilo lẹ́bàá odò tí ń ṣàn. +“Ẹnìkan yóo wí pé,‘OLUWA ló ni mí.’Ẹnìkejì yóo pe ara rẹ̀ ní orúkọ Jakọbu.Ẹlòmíràn yóo kọ ‘Ti OLUWA ni’ sí apá rẹ̀yóo máa fi orúkọ Israẹli ṣe àpèjá orúkọ rẹ̀.” +Gbọ́ ohun tí OLUWA, ọba Israẹli ati Olùràpadà rẹ̀ wí,OLUWA àwọn ọmọ ogun, ó ní,“Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀ ati ẹni òpin;lẹ́yìn mi, kò sí Ọlọrun mìíràn. +Ta ni ó dàbí mi? Kí olúwarẹ̀ sọ̀rọ̀kí ó kéde rẹ̀ níwájú mi.Ẹni tí ó bá ti kéde láti ìbẹ̀rẹ̀, nípa àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀,kí wọn sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa. +Má bẹ̀rù, má sì fòyà.Ṣebí mo ti sọ fún ọ tipẹ́,mo ti kéde rẹ̀,ìwọ sì ni ẹlẹ́rìí mi:Ǹjẹ́ Ọlọrun mìíràn wà lẹ́yìn mi?Kò tún sí àpáta kan mọ́, n kò mọ ọ̀kan kan.” +Asán ni àwọn tí ń gbẹ́ ère, ohun tí inú wọn dùn sí kò lérè. Àwọn tí ń jẹ́rìí wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ nǹkan, ojú ìbá le tì wọ́n. +OLUWA Yan Kirusi. +Ohun tí OLUWA sọ fún kirusi, ẹni tí ó fi àmì òróró yàn nìyí:Ẹni tí OLUWA di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, tí ó lò,láti rẹ àwọn orílẹ̀-èdè sílẹ̀ níwájú rẹ̀,láti tú àmùrè àwọn ọba,láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀,kí ẹnubodè má lè tì. +Ẹnìkan lè bi baba rẹ̀ pé:‘Irú kí ni o bí?’Tabi kí ó bi ìyá rẹ̀ léèrè pé:‘Irú ọmọ wo ni o bí yìí?’Olúwarẹ̀ gbé!” +OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ẹlẹ́dàá rẹ ni,“Ṣé ẹ óo máa bi mí ní ìbéèrè nípa àwọn ọmọ mi ni,tabi ẹ óo máa pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi? +Èmi ni mo dá ayé,tí mo dá eniyan sórí rẹ̀.Ọwọ́ mi ni mo fi ta ojú ọ̀run bí aṣọ,tí mo sì pàṣẹ fún oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀. +Èmi ni mo gbé Kirusi dìde ninu òdodo mi,n óo mú kí ó ṣe nǹkan bí ó ti tọ́;òun ni yóo tún ìlú mi kọ́,yóo sì dá àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní ìgbèkùn sílẹ̀,láìgba owó ati láìwá èrè kan.”OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀. +Ó ní, “Àwọn ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ẹrù ilẹ̀ Etiopia,ati àwọn ọkunrin Seba tí wọn ṣígbọnlẹ̀,wọn óo tọ̀ ọ́ wá, wọn óo di tìrẹ,wọn óo sì máa tẹ̀lé ọ.Wọn óo wá, pẹlu ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lẹ́sẹ̀ wọn,wọn óo sì wólẹ̀ fún ọ.Wọn óo máa bẹ̀ ọ́ pé,‘Lọ́dọ̀ rẹ nìkan ni Ọlọrun wà,kò tún sí Ọlọrun mìíràn.Kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ.’ ” +Nítòótọ́,ìwọ ni Ọlọrun tí ó ń fi ara pamọ́,Ọlọrun Israẹli, Olùgbàlà. +Gbogbo àwọn oriṣa ni a óo dójú tì,ìdààmú yóo sì bá wọn.Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ èreyóo bọ́ sinu ìdààmú papọ̀. +Ṣugbọn OLUWA gba Israẹli là,títí ayé sì ni ìgbàlà rẹ̀.Ojú kò ní tì ọ́, bẹ́ẹ̀ ni o kò ní dààmú, títí lae. +Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,OLUWA tí ó dá ọ̀run. (Òun ni Ọlọrun.)Òun ni ó dá ilẹ̀, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀,kò dá a ninu rúdurùdu,ṣugbọn ó dá a kí eniyan lè máa gbé inú rẹ̀Ó ní, “Èmi ni OLUWA, kò sí Ọlọrun mìíràn. +N kò sọ ọ́ níkọ̀kọ̀, ninu òkùnkùn.N kò sọ fún arọmọdọmọ Jakọbu pé:‘Ẹ máa wá mi ninu rúdurùdu.’Òtítọ́ ni Èmi OLUWA sọ.Ohun tí ó tọ́ ni mò ń kéde.” +OLUWA ní, “N óo lọ ṣáájú rẹ,n óo sọ àwọn òkè ńlá di pẹ̀tẹ́lẹ̀;n óo fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ,n óo sì gé ọ̀pá ìlẹ̀kùn irin. +OLUWA ní:“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ wá,ẹ jọ súnmọ́ bí,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kù ninu àwọn orílẹ̀-èdè.Aláìlóye ni àwọn tí ń gbẹ́ ère igi lásán kiri,tí wọ́n sì ń gbadurasí oriṣa tí kò lè gbànìyàn là. +Ẹ sọ̀rọ̀ jáde, kí ẹ sì ro ẹjọ́ tiyín,jẹ́ kí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀.Ta ló sọ èyí láti ìgbà laelae?Ta ló kéde rẹ̀ láti ìgbà àtijọ́?Ṣebí èmi OLUWA ni?Kò tún sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi.Ọlọrun Olódodo ati Olùgbàlàkò tún sí ẹnìkan mọ́, àfi èmi. +“Ẹ yipada sí mi kí á gbà yín là,gbogbo ẹ̀yin òpin ayé.Nítorí èmi ni Ọlọrun,kò tún sí ẹlòmíràn mọ́. +Mo ti fi ara mi búra, mo sì fi ẹnu mi sọ̀rọ̀ pẹlu òtítọ́ inú,ọ̀rọ̀ tí kò ní yipada:‘Gbogbo orúnkún ni yóo wólẹ̀ fún mi,èmi ni gbogbo eniyan yóo sì búra pé àwọn óo máa sìn.’ +“Nípa èmi nìkan ni àwọn eniyan yóo máa pé,‘Ninu OLUWA ni òdodo ati agbára wà.’Gbogbo àwọn tí ń bá a bínúyóo pada wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu ìtìjú. +Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun,wọn yóo sì ṣògo ninu OLUWA. +N óo fún ọ ní ìṣúra tí wọ́n fi pamọ́ sinu òkùnkùn,ati àwọn nǹkan tí wọ́n kó pamọ́ síkọ̀kọ̀;kí o lè mọ̀ pé èmi, OLUWA, Ọlọrun Israẹli,ni mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ. +Nítorí Jakọbu, iranṣẹ mi,ati Israẹli, àyànfẹ́ mi,mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ.Mo pe orúkọ rẹ ní àpèjá, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ mí. +“Èmi ni OLUWA kò sí ẹlòmíràn,kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi.Mo dì ọ́ ní àmùrè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò mọ̀ mí. +Kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀,kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.Èmi ni OLUWA, kò tún sí ẹlòmíràn. +Èmi ni mo dá ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn,èmi ni mo dá alaafia ati àjálù:Èmi ni OLUWA tí mo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi. +Rọ òjò sílẹ̀, ìwọ ọ̀run,kí ojú ọ̀run rọ̀jò òdodo sílẹ̀.Jẹ́ kí ilẹ̀ lanu, kí ìgbàlà lè yọ jáde.Jẹ́ kí ó mú kí òdodo yọ jáde pẹlu,èmi OLUWA ni mo ṣẹ̀dá rẹ̀ bẹ́ẹ̀. +“Ẹni tí ń bá ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà gbé! Ìkòkò tí ń bá amọ̀kòkò jà.Ṣé amọ̀ lè bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ń mọ ọ́n pé:‘Kí ni ò ń mọ?’Tabi kí ó sọ fún un pé,‘Nǹkan tí ò ń mọ kò ní ìgbámú?’ +“Oriṣa Bẹli tẹríba, oriṣa Nebo doríkodò.Orí àwọn ẹran ọ̀sìn ati mààlúù ni àwọn oriṣa wọn wà.Àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rù kiri wá di ẹrù, tí àwọn ẹranko tí ó ti rẹ̀ ń rù. +Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni èmi tíí sọ ohun tí ó gbẹ̀yìn.Láti ìgbà àtijọ́,ni mo tí ń sọ àwọn nǹkan tí kò ì tíì ṣẹlẹ̀.Èmi a máa sọ pé: ‘Àbá mi yóo ṣẹ,n óo sì mú ìpinnu mi ṣẹ.’ +Mo pe idì láti ìlà oòrùn,mo sì ti pe ẹni tí yóo mú àbá mi ṣẹ láti ilẹ̀ òkèèrè wá.Mo ti sọ̀rọ̀, n óo sì mú un ṣẹ,mo ti ṣe ìpinnu, n óo sì ṣe é. +“Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin aláìgbọràn, ẹ̀yin tí ẹ jìnnà sí ìgbàlà. +Mo mú ìdáǹdè mi wá sí tòsí, kò jìnnà mọ́,ìgbàlà mi kò ní pẹ́ dé.N óo fi ìgbàlà mi sí Sioni, fún Israẹli, ògo mi.” +Àwọn mejeeji jọ tẹríba, wọ́n jọ doríkodò,wọn ò lè gba àwọn ẹrù wọn kalẹ̀.Àwọn pàápàá yóo lọ sí ìgbèkùn. +“Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu,ati gbogbo ará ilé Israẹli tí ó ṣẹ́kù;ẹ̀yin tí mo pọ̀n láti ọjọ́ tí wọ́n ti bi yín,tí mo sì gbé láti inú oyún. +Èmi náà ni, títí di ọjọ́ ogbó yín,n óo gbé yín títí tí ẹ óo fi hewú lórí.Èmi ni mo da yín, n óo sì máa tọ́jú yín,n óo máa gbé yín, n óo sì gbà yín là. +“Ta ni ẹ óo fi mí wé?Ta ni ẹ óo fi díwọ̀n mi?Ta ni ẹ lè fi wé mi, kí á lè jọ jẹ́ bákan náà? +Àwọn kan ń kó ọpọlọpọ wúrà jáde ninu àpò,wọ́n sì ń wọn fadaka lórí ìwọ̀n.Wọ́n sanwó ọ̀yà fún alágbẹ̀dẹ wúrà, ó bá wọn fi dá oriṣa.Wọ́n wá ń foríbalẹ̀ fún un, wọ́n ń sìn ín. +Wọn á gbé e lé èjìká wọn,wọn á gbé e sípò rẹ̀, á sì dúró kabẹ̀.Kò ní le kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkankan.Bí eniyan bá ké pè é, kò lè gbọ́,kò lè yọ eniyan ninu ìṣòro rẹ̀. +“Ẹ ranti èyí, kí ẹ dà á rò,ẹ fi ọkàn rò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀. +Ẹ ranti àwọn nǹkan ti àtijọ́,nítorí pé èmi ni Ọlọrun, kò sí Ọlọrun mìíràn mọ́.Èmi ni Ọlọrun, kò sí ẹni tí ó dà bí mi. +Ìdájọ́ lórí Babiloni. +Sọ̀kalẹ̀ kí o jókòó ninu eruku, ìwọ Babiloni.Jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀, láìsí ìtẹ́-ọba,ìwọ ọmọbinrin Kalidea.A kò ní pè ọ́ ní ẹlẹgẹ́ ati aláfẹ́ mọ́. +“Ọkàn rẹ balẹ̀ ninu iṣẹ́ ibi rẹ,o ní ẹnìkan kò rí ọ.Ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ mú ọ ṣìnà,ò ń sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Èmi nìkan ní mo wà.Kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’ +Ṣugbọn ibi yóo dé bá ọ,tí o kò ní lè dáwọ́ rẹ̀ dúró;àjálù yóo dé bá ọ,tí o kò ní lè ṣe ètùtù rẹ̀;ìparun yóo dé bá ọ lójijì,tí o kò ní mọ nǹkankan nípa rẹ̀. +Múra sí àfọ̀ṣẹ rẹ,sì múra si oṣó ṣíṣẹ́ jọ,tí o ti dáwọ́ lé láti kékeré,bóyá o óo tilẹ̀ yege,tabi bóyá o sì lè dẹ́rùba eniyan. +Ọpọlọpọ ìmọ̀ràn tí wọn fún ọ ti sú ọ;jẹ́ kí wọn dìde nílẹ̀ kí wọ́n gbà ọ́ wàyí,àwọn tí ó ń wojú ọ̀run,ati àwọn awòràwọ̀;tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ,nígbà tí oṣù bá ti lé. +“Wò ó! Wọ́n dàbí àgékù koríko,iná ni yóo jó wọn ráúráú,wọn kò sì ní lè gba ara wọn kalẹ̀, ninu ọ̀wọ́ iná.Eléyìí kì í ṣe iná tí eniyan ń yá,kì í ṣe iná tí eniyan lè jókòó níwájú rẹ̀. +Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ rí sí ọ, àwọn tí ẹ ti jọ ń ṣòwò pọ̀ láti ìgbà èwe rẹ.Olukuluku wọn ti ṣìnà lọ,kò sí ẹni tí yóo gbà ọ́ sílẹ̀.” +Gbé ọlọ kí o máa lọ ọkà,ṣí aṣọ ìbòjú rẹ kúrò,ká aṣọ rẹ sókè, kí o ṣí ẹsẹ̀ rẹ sílẹ̀,kí o sì la odò kọjá. +A óo tú ọ sí ìhòòhò,a óo sì rí ìtìjú rẹ.N óo gbẹ̀san,n kò sì ní dá ẹnìkan kan sí. +Olùràpadà wa, tí ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli. +OLUWA wí nípa Kalidea pé:“Jókòó kí o dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí o sì wọ inú òkùnkùn lọ,ìwọ ọmọbinrin Kalidea.Nítorí a kò ní pè ọ́ ní ayaba àwọn orílẹ̀-èdè mọ́. +Inú bí mi sí àwọn eniyan mi,mo sì sọ nǹkan ìní mi di ohun ìríra.Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,o kò ṣàánú wọn.O di àjàgà wúwo rẹ mọ́ àwọn arúgbó lọ́rùn. +O sọ pé ìwọ ni o óo máa jẹ́ ayaba títí lae,nítorí náà o kò kó àwọn nǹkan wọnyi lékàn,o kò sì ranti ìgbẹ̀yìn wọn. +“Nítorí náà, gbọ́ nisinsinyii, ìwọ tí o fẹ́ràn afẹ́ ayé,tí o jókòó láìléwu,tí ò ń sọ lọ́kàn rẹ pé,‘Èmi nìkan ni mo wà,kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.N kò ní di opó,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní ṣòfò ọmọ.’ +Ọ̀fọ̀ mejeeji ni yóo ṣe ọ́ lójijì, lọ́jọ́ kan náà: o óo ṣòfò ọmọ, o óo sì di opó,ibi yìí yóo dé bá ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.Ò báà lóṣó, kí o lájẹ̀ẹ́,kí àfọ̀ṣẹ rẹ sì múná jù bẹ́ẹ̀ lọ. +Ọlọrun ni OLUWA Ọjọ́ Iwájú. +Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu,ẹ̀yin tí à ń fi orúkọ Israẹli pè,ọmọ bíbí inú Juda,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń forúkọ OLUWA búra,tí ẹ jẹ́wọ́ Ọlọrun Israẹli,ṣugbọn tí kì í ṣe pẹlu òdodo tabi òtítọ́. +Mo ti fọ̀ ọ́ mọ́,ṣugbọn kì í ṣe bí a tií fọ fadaka,mo dán yín wò ninu iná ìpọ́njú. +Nítorí tèmi, àní nítorí tèmi ni mo ṣe ṣe bẹ́ẹ̀.Nítorí kí ni ìdí rẹ̀ tí orúkọ mi yóo ṣe díbàjẹ́,n kò ní gbé ògo mi fún ẹlòmíràn. +“Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi ìwọ Jakọbu, ìwọ Israẹli, ẹni tí mo pè,Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀,èmi sì ni ẹni òpin. +Ọwọ́ mi ni mo fi fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,ọwọ́ ọ̀tún mi ni mo fi ta awọsanma sójú ọ̀run.Nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn jọ yọ síta. +“Gbogbo yín, ẹ péjọ, kí ẹ gbọ́,èwo ninu wọn ni ó kéde nǹkan wọnyi?OLUWA fẹ́ràn rẹ̀,yóo mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ lórí Babiloni,yóo sì gbógun ti àwọn ará Kalidea. +Èmi, àní èmi pàápàá ni mo sọ̀rọ̀, tí mo pè é,èmi ni mo mú un wá,yóo sì ṣe àṣeyege ninu àdáwọ́lé rẹ̀. +Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí,láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, n kò sọ̀rọ̀ ní àṣírí,láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe ni mo ti wà níbẹ̀.”Nisinsinyii, OLUWA, Ọlọrun, ati Ẹ̀mí rẹ̀ ti rán mi. +OLUWA, Olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ní,“Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ,tí ń kọ́ ọ ní ohun tí yóo ṣe ọ́ ní anfaani,tí ń darí rẹ, sí ọ̀nà tí ó yẹ kí o gbà. +“Ìbá jẹ́ pé o ti fetí sí òfin mi,alaafia rẹ ìbá máa ṣàn bí odò,òdodo rẹ ìbá lágbára bi ìgbì omi òkun. +Àwọn ọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí iyanrìn,arọmọdọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀ tí kò lóǹkà.Orúkọ wọn kì bá tí parẹ́ títí ayé,bẹ́ẹ̀ ni kì bá tí parun lae níwájú mi.” +Ẹ̀ ń pe ara yín ní ará ìlú mímọ́,ẹ fẹ̀yìn ti Ọl��run Israẹli,tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun. +Ẹ jáde kúrò ní Babiloni, ẹ sá kúrò ní Kalidea,ẹ sọ ọ́ pẹlu ayọ̀,ẹ kéde rẹ̀,ẹ máa ròyìn rẹ̀ lọ títí dè òpin ayé, pé“OLUWA ti ra Jakọbu iranṣẹ rẹ̀ pada.” +Òùngbẹ kò gbẹ wọ́n,nígbà tí ó mú wọn la inú aṣálẹ̀ kọjá,ó tú omi jáde fún wọn láti inú àpáta,ó la àpáta, omi sì tú jáde. +OLUWA sọ pé, “Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.” +OLUWA ní, “Láti ìgbà àtijọ́ ni mo ti kéde,àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀,èmi ni mo sọ wọ́n jáde,tí mo sì fi wọ́n hàn.Lójijì mo ṣe wọ́n,nǹkan tí mo sọ sì ṣẹ. +Nítorí mo mọ̀ pé alágídí ni yín,olóríkunkun sì ni yín pẹlu. +Mo ti sọ fun yín láti ọjọ́ pípẹ́:kí wọn tó ṣẹlẹ̀, mo ti kéde wọn fun yín,kí ẹ má baà sọ pé, ‘oriṣa wa ni ó ṣe wọ́n,àwọn ère wa ni ó pàṣẹ pé kí wọn ṣẹlẹ̀.’ +“Ẹ ti fetí ara yín gbọ́,nítorí náà, ẹ wo gbogbo èyí, ṣé ẹ kò ní kéde rẹ̀?Láti àkókò yìí lọ, n óo mú kí ẹ máa gbọ́ nǹkan tuntun,àwọn nǹkan tí ó farapamọ́ tí ẹ kò mọ̀. +Kò tíì pẹ́ tí a dá wọn,ẹ kò gbọ́ nípa wọn rí, àfi òní.Kí ẹ má baà wí pé:Wò ó, a mọ̀ wọ́n. +Ẹ kò gbọ́ ọ rí,bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀.Ọjọ́ ti pẹ́ tí a ti di yín létí,nítorí mo mọ̀ pé ẹ óo hùwà àgàbàgebè,ọlọ̀tẹ̀ ni orúkọ tí mo mọ̀ yín mọ̀,láti ìgbà tí ẹ ti jáde ninu oyún. +“Mo dáwọ́ ibinu mi dúró ná, nítorí orúkọ mi,nítorí ìyìn mi ni mo ṣe dá a dúró fun yín,kí n má baà pa yín run. +Israẹli, Ìmọ́lẹ̀ fún Ayé. +Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ilẹ̀ etí òkun. Ẹ fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè,láti inú oyún ni OLUWA ti pè mí,láti inú ìyá mi wá ni ó ti dárúkọ mi. +Ebi kò ní pa wọ́n, òùngbẹ kò sì ní gbẹ wọ́n,atẹ́gùn gbígbóná kò ní fẹ́ lù wọ́n,bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kò ní pa wọ́n,nítorí ẹni tí ó ṣàánú wọn ni yóo máa darí wọn,yóo sì mú wọn gba ẹ̀gbẹ́ omi tí ń ṣàn. +“N óo sọ gbogbo òkè mi di ojú ọ̀nà,n óo kún gbogbo òpópó ọ̀nà mi. +Wò ó! Òkèèrè ni èyí yóo ti wá,láti àríwá ati láti ìwọ̀ oòrùn, àní láti ilẹ̀ Sinimu.” +Kí ọ̀run kọrin ayọ̀, kí ayé kún fún ayọ̀,ẹ̀yin òkè, ẹ máa kọrin,nítorí, OLUWA ti tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu,yóo ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀ tí ìyà ń jẹ. +Sioni ń wí pé,“OLUWA ti kọ̀ mí sílẹ̀,Oluwa mi ti gbàgbé mi.” +OLUWA dáhùn pé, “Ǹjẹ́ abiyamọ le gbàgbé ọmọ tí ń fún lọ́mú?Ṣé ó le má ṣàánú ọmọ bíbí inú rẹ̀?Bí àwọn wọnyi tilẹ̀ gbàgbé.Èmi kò ní gbàgbé rẹ. +Wò ó! Mo ti fi gègé fín orúkọ rẹ sí àtẹ́lẹwọ́ mi,àwọn odi rẹ sì ńbẹ níwájú mi nígbà gbogbo. +“Àwọn ọmọ rẹ tí ń pada bọ̀ kíákíá,àwọn olùparun rẹ yóo jáde kúrò ninu rẹ. +Gbójú sókè, kí o wò yíká,gbogbo àwọn ọmọ rẹ péjọ, wọ́n tọ̀ ọ́ wá.OLUWA fi ara rẹ̀ búra pé,o óo gbé wọn wọ̀ bí nǹkan ọ̀ṣọ́ ara.O óo wọ̀ wọ́n bí ìgbà tí iyawo kó ohun ọ̀ṣọ́ wọ̀. +“Dájúdájú ilẹ̀ rẹ tí ó ti di aṣálẹ̀,ati àwọn tí ó ti di ahoro,yóo kéré fún àwọn tí yóo máa gbé inú rẹ̀ tí ó bá yá,a óo sì lé àwọn tí ó pa ọ́ run jìnnà sí ọ. +Ó ṣe ẹnu mi bí idà mímú, ó fi mí pamọ́ sí ibi òjìji ọwọ́ rẹ̀,ó ṣe mí ní ọfà tí ó mú,ó fi mí pamọ́ sinu apó rẹ̀. +Àwọn ọmọ tí o bí ní àkókò ìgbèkùn rẹyóo sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ pé,‘Ibí yìí kéré jù fún wa,fún wa ní àyè sí i láti máa gbé.’ +O óo bèèrè lọ́kàn ara rẹ nígbà náà pé,‘Ta ni ó bí àwọn ọmọ wọnyi fún mi?Ṣebí àwọn ọmọ mi ti kú, mo ti yàgàn,mo sì lọ sí ìgbèkùn lóko ẹrú.Ta ni ó wá tọ́ àwọn wọnyi dàgbà?Ṣebí èmi nìkan ni mo ṣẹ́kù,níbo ni àwọn wọnyi ti wá?’ ” +OLUWA Ọlọrun ní, “Wò ó, n óo gbé ọwọ́ mi sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè.N óo gbé àsíá mi sókè sí àwọn eniyan,wọn óo gbé àwọn ọmọ rẹ ọkunrin mọ́ àyà wọnwọn óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin sí èjìká. +Àwọn ọba ni yóo máa tọ́jú rẹ bíi baba,àwọn ayaba yóo sì máa tọ́jú rẹ bí ìyá,ní ìdojúbolẹ̀ ni wọn óo máa tẹríba fún ọ,wọn óo sì máa pọ́n eruku ẹsẹ̀ rẹ lá.O óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA,ojú kò ní ti àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé mi.” +Ǹjẹ́ a lè gba ìkógun lọ́wọ́ alágbára,tabi kí á gba òǹdè lọ́wọ́ òkúrorò eniyan? +OLUWA ní:“Bí ó bá tilẹ̀ ṣeéṣe láti gba òǹdè lọ́wọ́ alágbára,tabi láti gba ìkógun lọ́wọ́ òkúrorò eniyan.N óo bá àwọn tí ó ń bá ọ jà jà,n óo sì gba àwọn ọmọ rẹ là. +N óo mú kí àwọn tó ń ni ọ́ lára máa pa ara wọn jẹ:wọn óo máa mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn, bí ẹni mu ọtí,gbogbo ayé yóo sì mọ̀ nígbà náà pé,èmi ni OLUWA, Olùgbàlà rẹ,Olùràpadà rẹ, Ọlọrun alágbára Jakọbu.” +Ó sọ fún mi pé, “Iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli,àwọn eniyan óo máa yìn mí lógo nítorí rẹ.” +Ṣugbọn mo dáhùn pé,“Mo ti ṣiṣẹ́ àṣedànù.Mo ti lo agbára mi ṣòfò, mo ti fi ṣe àṣedànù,sibẹsibẹ ẹ̀tọ́ mi ń bẹ lọ́dọ̀ OLUWA.”Ẹ̀san mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọrun mi, yóo san án fún mi. +Nisinsinyii, OLUWA, tí ó ṣẹ̀dá mi ninu oyún,kí n lè jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, láti mú Jakọbu pada tọ̀ ọ́ wá,ati láti mú kí Israẹli kórajọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí mo níyì lójú OLUWA,Ọlọrun mi sì ti di agbára mi. +OLUWA ní nǹkan kékeré ni kí n jẹ́ iranṣẹ òun, láti gbé àwọn ẹ̀yà Jakọbu dìde, ati láti kó àwọn ọmọ Israẹli tí ó kù jọ.Ó ní òun óo fi mí ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdèkí ìgbàlà òun lè dé òpin ayé. +Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà Israẹli, ati Ẹni Mímọ́ rẹ̀, sọ,fún ẹni tí ayé ń gàn,tí àwọn orílẹ̀-èdè kórìíra,iranṣẹ àwọn aláṣẹ,ó ní, “Àwọn ọba yóo rí ọ, wọn óo dìde,àwọn ìjòyè yóo rí ọ, wọn óo sì dọ̀bálẹ̀.Nítorí OLUWA, tí ó jẹ́ olódodo,Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ti yàn ọ́.” +OLUWA ní, “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mo dá ọ lóhùn,lọ́jọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.Mo ti pa ọ́ mọ́,mo sì ti fi ọ́ dá majẹmu pẹlu àwọn aráyé,láti fìdí ilẹ̀ náà múlẹ̀,láti pín ilẹ̀ tí ó ti di ahoro. +Kí o máa sọ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé, ‘Ẹ jáde,’ati fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn pé, ‘Ẹ farahàn.’Wọn óo rí ohun jíjẹ ní gbogbo ọ̀nà,gbogbo orí òkè yóo sì jẹ́ ibùjẹ fún wọn. +Orin Ọgbà Àjàrà. +Ẹ jẹ́ kí n kọrin kan fún olùfẹ́ mi,kí n kọrin nípa ọgbà àjàrà rẹ̀.Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kanní orí òkè kan tí ilẹ̀ ibẹ̀ lọ́ràá. +Apẹ̀rẹ̀ èso àjàrà kan ni a óo rí ká ninu ọgbà àjàrà sarè mẹ́wàá.Kóńgò èso kan ni ẹni tí ó gbin kóńgò marun-un yóo rí ká.” +Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ kutukutu,láti máa wá ọtí líle kiri,tí wọ́n ń mu ún títí di ìrọ̀lẹ́,títí tí ọtí yóo fi máa pa wọ́n! +Dùùrù, hapu, ìlù, fèrè ati ọtí waini wà níbi àsè wọn;ṣugbọn wọn kì í bìkítà fún iṣẹ́ Ọlọrun,wọn kìí sìí náání iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. +Nítorí náà àwọn eniyan mi óo lọ sí oko ẹrú nítorí àìmòye wọn,ebi ni yóo pa àwọn ọlọ́lá wọn ní àpakú,òùngbẹ óo sì gbẹ ọpọlọpọ wọn. +Isà òkú ti ṣetán, yóo gbé wọn mì,ó ti yanu kalẹ̀.Àwọn ọlọ́lá Jerusalẹmu yóo já sinu rẹ́,ati ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará ìlú,ati àwọn tí ń fi ìlú Jerusalẹmu yangàn. +A tẹ eniyan lórí ba,a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ojú àwọn onigbeeraga yóo sì wálẹ̀. +Ṣugbọn OLUWA àwọn ọmọ ogunni a óo gbéga ninu ẹ̀tọ́ nítorí ìdájọ́ òdodoỌlọrun Mímọ́ yóo fi ara rẹ̀ hàn, pé mímọ́ ni òun ninu òdodo. +Nígbà náà ni àwọn ọ̀dọ́ aguntan yóo máa jẹ oko ninu pápá oko wọnàwọn àgbò ati ewúrẹ́ yóo sì máa jẹko ninu ahoro wọn. +Àwọn tí ń ṣe àfọwọ́fà ẹ̀ṣẹ̀ gbé!Àwọn tí wọn ń fi ìwà aiṣododo fa ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni tí ń fi okùn fa ẹṣin. +Tí wọn ń wí pé:“Kí ó tilẹ̀ ṣe kíá,kí ó ṣe ohun tí yóo ṣe, kí á rí i.Jẹ́ kí àbá Ẹni Mímọ́ Israẹli di òtítọ́kí ó ṣẹlẹ̀, kí á lè mọ̀ ọ́n!” +Ó kọ́ ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣa gbogbo òkúta ibẹ̀ kúrò. Ó gbin àjàrà dáradára sinu rẹ̀.Ó kọ́ ilé ìṣọ́ gíga sí ààrin rẹ̀,ó sì ṣe ibi tí wọn yóo ti máa fún ọtí sibẹ.Ó ń retí kí àjàrà rẹ̀ so,ṣugbọn èso kíkan ni ó so. +Àwọn tí ń pe ibi ní ire gbé;tí wọn ń pe ire ní ibi!Àwọn tí wọn ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀,tí wọn sì fi ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn!Tí wọ́n fi ìkorò ṣe adùn,tí wọ́n sì fi adùn ṣe ìkorò. +Àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn gbé;tí wọ́n ka ara wọn kún ẹni tí ó ní ìmọ̀! +Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá ninu ọtí mímu gbé;tí wọ́n jẹ́ akikanjubí ó bá di pé kí á da ọtí líle pọ̀ mọ́ ara wọn! +Àwọn tí wọn ń dá ẹni tí ó jẹ̀bi sílẹ̀nígbà tí wọ́n bá ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tán;tí wọn kì í jẹ́ kí aláìṣẹ̀ rí ẹ̀tọ́ gbà. +Nítorí náà, bí iná tíí jó àgékù igi kanlẹ̀,tíí sìí jó ewéko ní àjórun;bẹ́ẹ̀ ní gbòǹgbò wọn yóo ṣe rà,tí ìtànná wọn yóo sì fẹ́ lọ bí eruku.Nítorí wọ́n kọ òfin OLUWA àwọn ọmọ ogun sílẹ̀,wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli. +Nítorí náà ni inú ṣe bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀,ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa wọ́n,àwọn òkè sì mì tìtì.Òkú wọn dàbí pàǹtí láàrin ìgboro,sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò sì dá ọwọ́ ìjà dúró. +Ó ta àsíá, ó fi pe orílẹ̀-èdè kan tí ó wà ní òkèèrè;ó sì fọn fèrè sí i láti òpin ayé.Wò ó! Àwọn eniyan orílẹ̀-èdè náà ń bọ̀ kíákíá. +Kò rẹ ẹnikẹ́ni ninu wọn,ẹnikẹ́ni ninu wọn kò fẹsẹ̀ kọ.Ẹyọ ẹnìkan wọn kò sì sùn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tòògbé.Àmùrè ẹnìkankan kò tú,bẹ́ẹ̀ ni okùn bàtà ẹnìkankan kò já. +Ọfà wọn mú wọ́n kẹ́ ọrun wọn.Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin wọn le bí òkúta akọ;ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn dàbí ìjì líle. +Bíbú wọn dàbí ti kinniun,wọn a bú ramúramù bí ọmọ kinniun,wọn a kígbe, wọn a sì ki ohun ọdẹ wọn mọ́lẹ̀,wọn a gbé e lọ, láìsí ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ wọn. +Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ati ẹ̀yin ará Juda,mo bẹ̀ yín, ẹ wá ṣe ìdájọ́ láàrin èmi ati ọgbà àjàrà mi. +Wọn óo hó lé Israẹli lórí lọ́jọ́ náàbí ìgbà tí omi òkun ń hó.Bí eniyan bá wọ ilẹ̀ náà yóo rí òkùnkùn ati ìnira.Ìkùukùu rẹ̀ yóo sì bo ìmọ́lẹ̀. +Kí ló tún kù tí ó yẹ kí n ṣe sí ọgbà àjàrà mi tí n kò ṣe?Ìgbà tí mo retí kí ó so èso dídùn,kí ló dé tí ó fi so èso kíkan? +Nisinsinyii n óo sọ ohun tí n óo ṣe sí ọgbà àjàrà mi fun yín.N óo tú ọgbà tí mo ṣe yí i ká,iná yóo sì jó o.N óo wó odi tí mo mọ yí i ká,wọn yóo sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. +N óo jẹ́ kí ó di igbó,ẹnikẹ́ni kò ní ro ó mọ́,wọn kò sì ní tọ́jú rẹ̀ mọ́.Ẹ̀gún ati ẹ̀wọ̀n agogo ni yóo hù níbẹ̀.N óo pàṣẹ fún òjòkí ó má rọ̀ sórí rẹ̀ mọ́. +Nítorí ilé Israẹli ni ọgbà àjàrà OLUWA ọmọ ogun,àwọn ará Juda ni àjàrà dáradára tí ó gbìn sinu rẹ̀.Ó ń retí kí wọn máa ṣe ẹ̀tọ́,ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń paniyan;ó ń retí ìwà òdodo,ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọn ń ni lára ni wọ́n ń kígbe. +Ègbé ni fún àwọn tí ó ń kọ́lé mọ́lé,tí wọn ń gba ilẹ̀ kún ilẹ̀,títí tí kò fi sí ilẹ̀ mọ́,kí ẹ̀yin nìkan baà lè máa gbé ilẹ̀ náà. +OLUWA ọmọ ogun ti búra lójú mi, ó ní,“Láìsí àní-àní, ọpọlọpọ ilé ni yóo di ahoro,ọ̀pọ̀ ilé ńláńlá, ati ilé dáradára yóo sì wà láìsí olùgbé. +Ìgbọràn Iranṣẹ OLUWA. +OLUWA ní: OLUWA ní:“Ìwé ìkọ̀sílẹ̀ tí mo fi kọ àwọn eniyan mi sílẹ̀ dà?Ta ni mo tà yín fún,tí mo jẹ lówó?Ẹ wò ó! Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ni a ṣe tà yín,nítorí àìdára yín ni mo ṣe kọ̀ yín sílẹ̀. +Ta ló bẹ̀rù OLUWA ninu yín,tí ń gbọ́ràn sí iranṣẹ rẹ̀ lẹ́nu,tí ń rìn ninu òkùnkùn,tí kò ní ìmọ́lẹ̀,ṣugbọn sibẹ, tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,tí ó fẹ̀yìn ti Ọlọrun rẹ̀. +Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dáná,tí ẹ tan iná yí ara yín ká,ẹ máa rìn lọ ninu iná tí ẹ dá;ẹ máa la iná tí ẹ fi yí ara yín ká kọjá.Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fun yín.Ẹ óo wà ninu ìrora. +“Kí ló dé tí mo wá àwọn eniyan mi tí n kò rí ẹnìkan;mo pè, ẹnikẹ́ni kò dá mi lóhùn?Ṣé n kò lágbára tó láti rà wọ́n pada ni;àbí n kò lágbára láti gba ni là?Wò ó! Ìbáwí lásán ni mo fi gbẹ́ omi òkun,tí mo sì fi sọ odò tí ń ṣàn di aṣálẹ̀,omi wọn gbẹ,òùngbẹ gbẹ àwọn ẹja inú wọn pa,wọ́n kú, wọ́n sì ń rùn. +Mo da òkùnkùn bo ojú ọ̀run bí aṣọ,mo ṣe aṣọ ọ̀fọ̀ ní ìbora fún wọn.” +OLUWA Ọlọrun ti fi ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sí mi lẹ́nu.Kí n lè mọ bí a tií gba àwọn tí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì níyànjú.Ojoojumọ ni ó ń ṣí mi létí láràárọ̀,kí n lè máa gbọ́rọ̀ bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́. +OLUWA Ọlọrun ti ṣí mi létí,n kò sì ṣe oríkunkun,tabi kí n pada sẹ́yìn. +Mo tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ fún àwọn tí ń nani lẹ́gba; mo sì kọ ẹ̀rẹ̀kẹ́ sí àwọn tí ń fa eniyan ní irùngbọ̀n tu.N kò fojú pamọ́ nítorí ẹ̀gàn,bẹ́ẹ̀ ni n kò gbójú sá fún itọ́ títu síni lójú. +OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́,nítorí náà ojú kò tì mí;nítorí náà mo múra gírí,mo jẹ́ kí ojú mi le koko,mo sì mọ̀ pé ojú kò ní tì mí. +Ẹni tí yóo dá mi láre wà nítòsí,ta ló fẹ́ bá mi jà?Ta ló fẹ́ fi ẹ̀sùn kàn mí?Kí olúwarẹ̀ súnmọ́ tòsí mi,kí á jọ kojú ara wa? +Wò ó! OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́, ta ni yóo dá mi lẹ́bi?Gbogbo wọn ni yóo gbọ̀n dànù bí aṣọ,kòkòrò yóo sì jẹ wọ́n. +Ọ̀rọ̀ Ìtùnú fún Jerusalẹmu. +“Ẹ gbọ́ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sáré ìdáǹdè,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá OLUWA,ẹ wo àpáta tí a mú lára rẹ̀, tí a fi gbẹ yín,ati kòtò ibi tí a ti wà yín jáde. +Àbí ìwọ kọ́ ni o mú kí omi òkun gbẹ,omi inú ọ̀gbun ńlá;tí o sọ ilẹ̀ òkun di ọ̀nà,kí àwọn tí o rà pada lè kọjá? +Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada wá,pẹlu orin ni wọn óo pada wá sí Sioni.Adé ayọ̀ ni wọn óo dé sórí,wọn óo láyọ̀, inú wọn yóo dùn;ìbànújẹ́ ati ẹ̀dùn wọn yóo sì fò lọ. +“Èmi fúnra mi ni mò ń tù ọ́ ninu,ta ni ọ́, tí o fi ń bẹ̀rù eniyan tí yóo kú?Ìwọ ń bẹ̀rù ọmọ eniyan tí a dá, bíi koríko. +O gbàgbé OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ,tí ó ta ojú ọ̀run bí aṣọ,tí ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀.O wá ń fi gbogbo ọjọ́ ayé bẹ̀rù ibinu àwọn aninilára,nítorí wọ́n múra tán láti pa ọ́ run?Ibinu àwọn aninilára kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́. +Láìpẹ́, a óo tú àwọn tí a tẹ̀ lórí ba sílẹ̀.Wọn kò ní kú, wọn kò ní wọ inú isà òkú,wọn kò sì ní wá oúnjẹ tì. +“Nítorí èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ,ẹni tí ó rú òkun sókè,tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo;OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ mi. +Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu,mo ti pa ọ́ mọ́ lábẹ́ òjìji ọwọ́ mi.Èmi ni mo fi ojú ọ̀run sí ipò rẹ̀,tí mo fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,tí mo sì sọ fún ìlú Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni eniyan mi.’ ” +Jí, jí! Dìde, ìwọ Jerusalẹmu. Ìwọ tí o ti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibinu OLUWA,ìwọ tí OLUWA ti fi ibinu jẹ níyà,tí ojú rẹ wá ń pòòyì. +Kò sí ẹni tí yóo tọ́ ọ sọ́nà,ninu gbogbo àwọn ọmọ tí o ti bí,kò sí ẹni tí yóo fà ọ́ lọ́wọ́,ninu gbogbo ọmọ tí o tọ́ dàgbà. +Àjálù meji ló dé bá ọ,ta ni yóo tù ọ́ ninu:Ìsọdahoro ati ìparun, ìyàn ati ogun,ta ni yóo tù ọ́ ninu? +Ẹ wo Abrahamu baba yín,ati Sara tí ó bi yín.Òun nìkan ni nígbà tí mo pè é,tí mo súre fún un,tí mo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ eniyan. +Àárẹ̀ mú àwọn ọmọ rẹ,wọ́n sùn káàkiri ní gbogbo òpópó,bí ìgalà tí ó bọ́ sinu àwọ̀n.Ibinu OLUWA rọ̀jò lé wọn lórí,àní ìbáwí Ọlọrun rẹ. +Nítorí náà, ẹ̀yin tí à ń fi ìyà jẹ, ẹ gbọ́ èyí;ẹ̀yin tí ẹ ti yó láì tíì mu ọtí, +Oluwa rẹ, àní OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní,“Wò ó! Mo ti gba ife àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n lọ́wọ́ rẹ,O kò ní rí ibinu mi mọ́. +Àwọn tí ń dá ọ lóró ni yóo rí ibinu mi,àwọn tí ó wí fún ọ pé,‘Bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí á gba orí rẹ kọjá;’tí wọ́n sọ ẹ̀yìn rẹ di ilẹ̀ẹ́lẹ̀,tí wọ́n sọ ọ́ di ojú ọ̀nà wọn, tí wọn óo máa gbà kọjá.” +“OLUWA yóo tu Sioni ninu,yóo tu gbogbo àwọn tí ó ṣòfò ninu rẹ̀ ninu;yóo sì sọ aṣálẹ̀ rẹ̀ dàbí Edẹni, ọgbà OLUWA.Ayọ̀ ati ìdùnnú ni yóo máa wà ninu rẹ̀,pẹlu orin ọpẹ́ ati orin ayọ̀. +“Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin eniyan mi,ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,òfin kan yóo ti ọ̀dọ̀ mi jáde,ìdájọ́ òdodo mi yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan. +Ìdáǹdè mi súnmọ́ tòsí,ìgbàlà mi sì ti ń yọ bọ̀.Èmi ni n óo máa ṣe àkóso àwọn eniyan,àwọn erékùṣù yóo gbẹ́kẹ̀lé mi,ìrànlọ́wọ́ mi ni wọn yóo sì máa retí. +Ẹ gbójú sókè, ẹ wo ojú ọ̀run,kí ẹ sì wo ayé ní ìsàlẹ̀.Ọ̀run yóo parẹ́ bí èéfín,ayé yóo gbó bí aṣọ,àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ yóo sì kú bíi kòkòrò;ṣugbọn títí lae ni ìgbàlà mi,ìdáǹdè mi kò sì ní lópin. +“Ẹ̀yin tí ẹ mọ òdodo, ẹ gbọ́ ohùn mi,ẹ̀yin tí ẹ fi tọkàntọkàn gba òfin mi,ẹ má bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn eniyan;ẹ má sì jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ wọn já a yín láyà. +Ikán yóo jẹ wọ́n bí aṣọ,kòkòrò yóo jẹ wọ́n bí òwú;ṣugbọn ìdáǹdè mi yóo wà títí lae,ìgbàlà mi yóo sì wà láti ìran dé ìran.” +Jí, jí! Dìde, OLUWA, jí pẹlu agbára;jí bí ìgbà àtijọ́,bí o ti ṣe sí ìran wa látijọ́.Ṣebí ìwọ ni o gé Rahabu wẹ́lẹwẹ̀lẹ,tí o fi idà gún diragoni? +Ọlọrun Yóo Gba Jerusalẹmu. +Jí, Sioni, jí! Gbé agbára rẹ wọ̀ bí aṣọ,gbé ẹwà rẹ wọ̀ bí ẹ̀wù,ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́;nítorí àwọn aláìkọlà ati aláìmọ́, kò ní wọ inú rẹ mọ́. +OLUWA yóo lo agbára mímọ́ rẹ̀, lójú àwọn orílẹ̀-èdè,gbogbo eniyan, títí dé òpin ayé, yóo sì rí ìgbàlà Ọlọrun wa. +Ẹ jáde, ẹ jáde ẹ kúrò níbẹ̀, ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan,ẹ jáde kúrò láàrin rẹ̀, kí ẹ sì wẹ ara yín mọ́,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò OLUWA. +Nítorí pé ẹ kò ní fi ìkánjú jáde,bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní sáré jáde.Nítorí OLUWA yóo máa lọ níwájú yín,Ọlọrun Israẹli yóo sì wà lẹ́yìn yín. +Wò ó! Iranṣẹ mi yóo ṣe àṣeyọría óo gbé e ga, a óo gbé e lékè;yóo sì di ẹni gíga, +Ẹnu ti ya ọpọlọpọ eniyan nítorí rè��.Wọ́n bà á lójú jẹ́ yánnayànna,tóbẹ́ẹ̀ tí ìrísí rẹ̀ kò fi jọ ti eniyan mọ́. +Bẹ́ẹ̀ ni yóo di ohun ìyanu fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, kẹ́kẹ́ yóo pamọ́ àwọn ọba wọn lẹ́nu,nígbà tí wọ́n bá rí i,wọn óo rí ohun tí wọn kò gbọ́ rí nípa rẹ̀,òye ohun tí wọn kò mọ̀ rí yóo yé wọn. +Dìde, gbọnranù kúrò ninu erùpẹ̀,ìwọ Jerusalẹmu tí ó wà ninu ìdè.Tú okùn tí a dè mọ́ ọ lọ́rùn kúrò,ìwọ Sioni tí ó wà ninu ìdè. +Nítorí OLUWA ní, “Ọ̀fẹ́ ni a mu yín lẹ́rú, ọ̀fẹ́ náà sì ni a óo rà yín pada. +Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn eniyan mi lọ ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà, àwọn ará Asiria pọ́n wọn lójú láì nídìí. +Ṣugbọn nisinsinyii, kí ni mo rí yìí? Wọ́n mú àwọn eniyan mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn alákòóso wọn ń pẹ̀gàn, orúkọ mi wá di nǹkan yẹ̀yẹ́? +Nítorí náà àwọn eniyan mi yóo mọ orúkọ mi, wọn óo sì mọ̀ ní ọjọ́ náà pé, èmi tí mò ń sọ̀rọ̀, èmi náà nìyí.” +Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìyìn rere bọ̀ ti dára tó lórí òkè, ẹni tí ń kéde alaafia,tí ń mú ìyìn rere bọ̀,tí sì ń kéde ìgbàlà,tí ń wí fún Sioni pé,“Ọlọrun rẹ jọba.” +Gbọ́, àwọn aṣọ́de rẹ gbóhùn sókè,gbogbo wọn jọ ń kọrin ayọ̀,nítorí wọ́n jọ fi ojú ara wọn rí i,tí OLUWA pada dé sí Sioni. +Ẹ jọ máa kọrin pọ̀,gbogbo ilẹ̀ Jerusalẹmu tí a sọ di aṣálẹ̀,nítorí OLUWA yóo tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu,yóo ra Jerusalẹmu pada. +Ta ló lè gba ìyìn tí a rò gbọ́? Ta ni a ti fi agbára OLUWA hàn? +Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára,ó sì fi í sinu ìbànújẹ́,nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;yóo fojú rí ọmọ rẹ̀,ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn.Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀. +Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀,yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo,yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre,yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn. +Nítorí náà, n óo fún un ní ìpín, láàrin àwọn eniyan ńlá,yóo sì bá àwọn alágbára pín ìkógun,nítorí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú,wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.Sibẹsibẹ ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan,ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. +Ó dàgbà níwájú rẹ̀ bí nǹkan ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rúwéati bíi gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ.Ìrísí rẹ̀ kò dára,ojú rẹ̀ kò fanimọ́ra,bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹwà tí ìbá fi wu eniyan. +Àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀,wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀;ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí ó sì mọ ìkáàánú ni.Ó dàbí ẹni tí àwọn eniyan ń wò ní àwòpajúdà.A kẹ́gàn rẹ̀, a kò sì kà á kún. +Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ, ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa;sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà,tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. +Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa, wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa;ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia,nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá. +Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan, olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀,OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí. +Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú, sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀,wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa,ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀. +Wọ́n mú un lọ tipátipá, lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́,ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi péwọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè,ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án? +Wọ́n tẹ́ ẹ sí ibojì, pẹlu àwọn eniyan burúkú, wọ́n sì sin ín pẹlu ọlọ́rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe ẹnikẹ́ni níbi,kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. +Ìfẹ́ OLUWA sí Israẹli. +Máa kọrin! Ìwọ àgàn tí kò bímọ. Máa kọrin sókè, ìwọ tí kò rọbí rí.Nítorí ọmọ ẹni tí ọkọ ṣátì pọ̀,ju ọmọ ẹni tí ń gbé ilé ọkọ lọ,OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +Bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣí kúrò, tí a sì ṣí àwọn òkè kéékèèké nídìí,ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀, kò ní yẹ̀ lára rẹ,majẹmu alaafia mi tí mo bá ọ dá kò ní yẹ̀.Èmi OLUWA tí mo ṣàánú fún ọ ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +OLUWA ní:“Jerusalẹmu, ìwọ ẹni tí a pọ́n lójú, tí hílàhílo bá, tí a kò sì tù ninu,òkúta tí a fi oríṣìíríṣìí ọ̀dà kùn ni n óo fi kọ́ ọ,òkúta safire ni n óo sì fi ṣe ìpìlẹ̀ rẹ. +Òkúta Agate ni n óo fi ṣe ṣóńṣó ilé rẹ, òkúta dídán ni n óo fi ṣe ẹnu ọ̀nà ibodè rẹ,àwọn òkúta olówó iyebíye ni n óo fi mọ odi rẹ. +“Gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ni OLUWA yóo kọ́ wọn yóo sì ṣe ọpọlọpọ àṣeyọrí. +A óo fìdí rẹ múlẹ̀, ninu òdodo,o óo jìnnà sí ìnira, nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà ọ́.O óo jìnnà sí ìpayà, nítorí kò ní súnmọ́ ọ. +Bí ẹnìkan bá dojú ìjà kọ ọ́, kìí ṣe èmi ni mo rán an,ẹnikẹ́ni tó bá gbéjà kò ọ́, yóo ṣubú nítorí rẹ.” +OLUWA ní,“Wò ó! Èmi ni mo dá alágbẹ̀dẹ,tí ó fi ẹwìrì fẹ́ná,tí ó sì rọ àwọn ohun ìjà, fún ìlò rẹ̀,èmi náà ni mo dá apanirun,pé kí ó máa panirun. +Kò sí ohun ìjà tí a ṣe láti fi bá ọ jàtí yóo lágbára lórí rẹ.Gbogbo ẹni tí ó bá bá ọ rojọ́ nílé ẹjọ́,ni o óo jàre wọn.Èyí ni ìpín àwọn iranṣẹ OLUWA,ati ìdáláre wọn lọ́dọ̀ mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Fẹ ààyè àgọ́ rẹ sẹ́yìn,sì jẹ́ kí aṣọ tí ó ta sórí ibùgbé rẹ gbòòrò sí i, má ṣẹ́wọ́ kù.Na okùn àgọ́ rẹ kí ó gùn,kí o sì kan èèkàn rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí ó lágbára. +Nítorí o óo tàn kálẹ̀, sí apá ọ̀tún ati apá òsì,àwọn ọmọ rẹ yóo gba ìtẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè,wọn óo sì máa gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro. +Má bẹ̀rù nítorí ojú kò ní tì ọ́,má sì dààmú, nítorí a kì yóo dójú tì ọ́,nítorí o óo gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ,o kò sì ní ranti ẹ̀sín ìgbà tí o jẹ́ opó mọ́. +Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ,OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ,Ọlọrun gbogbo ayé ni à ń pè é. +Nítorí OLUWA ti pè ọ́,bí iyawo tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́,àní, bí iyawo àárọ̀ ẹni, tí a kọ̀ sílẹ̀;OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +Mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀,ṣugbọn n óo kó ọ jọ pẹlu ọpọlọpọ àánú. +Mo fojú mi pamọ́ fún ọ,fún ìgbà díẹ̀ nítorí inú mi ń ru sí ọ,ṣugbọn nítorí ìfẹ́ àìlópin mi, n óo ṣàánú fún ọ.Èmi OLUWA, Olùràpadà rẹ ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Bí ìgbà ayé Noa ni Ọ̀rọ̀ yìí rí sí mi: mo búra nígbà náà, pé omi Noa kò ní bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́.Bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra nisinsinyii,pé n kò ní bínú sí ọ mọ́,pé n kò ní bá ọ wí mọ́. +Àánú Ọlọrun. +OLUWA ní, “Gbogbo ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ,ẹ máa bọ̀ níbi tí omi wà;bí ẹ kò tilẹ̀ lówó lọ́wọ́,ẹ wá ra oúnjẹ kí ẹ sì jẹ.Ẹ wá ra ọtí waini láì mú owó lọ́wọ́,kí ẹ sì ra omi wàrà, tí ẹnikẹ́ni kò díyelé. +“Bí òjò ati yìnyín, tí ń rọ̀ láti ojú ọ̀run, tí wọn kì í pada sibẹ mọ́,ṣugbọn tí wọn ń bomi rin ilẹ̀,tí ń mú kí nǹkan hù jáde;kí àgbẹ̀ lè rí èso gbìn,kí eniyan sì rí oúnjẹ jẹ. +Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu mi yóo rí,kò ní pada sí ọ̀dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo,ṣugbọn yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ kí ó ṣe,yóo sì ṣe é ní àṣeyọrí. +“Nítorí tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa jáde ní Babiloni,alaafia ni wọ́n óo fi máa sìn yín sọ́nà,òkè ńlá ati kéékèèké yóo máa kọrin níwájú yín.Gbogbo igi inú igbó yóo sì máa pàtẹ́wọ́, +igi Sipirẹsi ni yóo máa hù dípò igi ẹlẹ́gùn-ún,igi Mitili ni yóo sì máa hù dípò ẹ̀gún ọ̀gàn,yóo jẹ́ àmì ìrántí fún OLUWA,ati àpẹẹrẹ ayérayé tí a kò ní parẹ́.” +Kí ló dé tí ẹ̀ ń ná owó yín lórí ohun tí kì í ṣe oúnjẹ? Tí ẹ sì ń ṣe làálàá lórí ohun tí kì í tẹ́ni lọ́rùn?Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára,kí ẹ sì jẹ ohun tí ó dára,ẹ jẹ oúnjẹ aládùn, kí inú yín ó dùn. +“Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, ẹ gbọ́ ohun tí mò ń wí kí ẹ lè yè.N óo ba yín dá majẹmu ayérayé,ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ tí mo ṣe ìlérí fún Dafidi. +Wò ó! Mo fi í ṣe olórí fún àwọn eniyan,olórí ati aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè. +O óo pe àwọn orílẹ̀-èdè tí o kò mọ̀ rí,àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́ rí yóo sáré wá sọ́dọ̀ rẹ,nítorí OLUWA Ọlọrun rẹ,ati nítorí Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ṣe ọ́ lógo.” +Ẹ wá OLUWA nígbà tí ẹ lè rí i,ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí. +Kí eniyan burúkú fi ọ̀nà ibi rẹ̀ sílẹ̀,kí alaiṣododo kọ èrò burúkú rẹ̀ sílẹ̀,kí ó yipada sí OLUWA,kí OLUWA lè ṣàánú rẹ̀.Kí ó yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun wa,nítorí Ọlọrun yóo dáríjì í lọpọlọpọ. +OLUWA ní,“Nítorí èrò tèmi yàtọ̀ sí tiyín,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi yàtọ̀ sí tiyín, +Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín,tí èrò mi sì ga ju èrò yín. +Gbogbo Orílẹ̀-Èdè ni yóo Wà lára Àwọn Eniyan Ọlọrun. +OLUWA ní: “Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́,kí ẹ sì máa ṣe òdodo;nítorí ìgbàlà mi yóo dé láìpẹ́,ẹ óo sì rí ìdáǹdè mi. +Afọ́jú ni àwọn aṣọ́de Israẹligbogbo wọn kò mọ nǹkankan.Ajá tí ó yadi ni wọ́n,wọn kò lè gbó;oorun ni wọ́n fẹ́ràn.Wọn á dùbúlẹ̀, wọn á máa lá àlá. +Wọ̀bìà ni wọ́n, alájẹkì,wọn kì í yó.Àwọn olùdarí wọn pàápàá kò mọ nǹkankan.Gbogbo wọn ti tẹ̀ sí ọ̀nà ara wọn,olukuluku wọn ń wá èrè fún ara rẹ̀. +Wọn á máa sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á mu waini,ẹ jẹ́ kí á mu ọtí líle ní àmuyó,bí òní ṣe rí ni ọ̀la yóo rí, yóo dùn tayọ.” +Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀,ati fún ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé e,tí ó ń ṣọ́ra, tí kò rú òfin ọjọ́ ìsinmi,tí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe nǹkan burúkú.” +Kí àjèjì tí ó faramọ́ OLUWA má sọ pé,“Dájúdájú OLUWA yóo yà mí kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.”Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé,“Wò ó! Mo dàbí igi gbígbẹ.” +Nítorí OLUWA ní,“Bí ìwẹ̀fà kan bá pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,tí ó bá ṣe ohun tí mo fẹ́,tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin, +n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi,ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ.Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn. +“Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín,tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀,gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra,tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin, +n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi,n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi.Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi;nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.” +OLUWA Ọlọrun tí ń kó àwọn tí ogun túká ní Israẹli jọ sọ pé,“N óo tún kó àwọn mìíràn jọ,kún àwọn tí mo ti kọ́ kó jọ.” +Gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti òkèèrè, ẹ máa bọ̀,gbogbo yín ẹ máa bọ̀ bí ẹranko inú ìgbẹ́, ẹ wá jẹ àjẹrun. +OLUWA Dá Ìwà Ìbọ̀rìṣà Israẹli lẹ́bi. +Olódodo ń ṣègbé,kò sí ẹni tí ó fi ọkàn sí i.A mú àwọn olótìítọ́ kúrò, kò sì sí ẹni tí ó yé,pé à ń yọ olódodo kúrò ninu ìdààmú ni. +Àárẹ̀ mú ọ nítorí ìrìn àjò rẹ jìnnà,sibẹsibẹ o kò sọ fún ara rẹ pé, “Asán ni ìrìn àjò yìí.”Ò ń wá agbára kún agbára,nítorí náà àárẹ̀ kò mú ọ. +Ta ni ń já ọ láyà,tí ẹ̀rù rẹ̀ bà ọ́, tí o fi purọ́;tí o kò ranti mi, tí o kò sì ronú nípa mi?Ṣé nítorí mo ti dákẹ́ fún ìgbà pípẹ́,ni o kò fi bẹ̀rù mi? +N óo sọ nípa òdodo rẹ ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,ṣugbọn wọn kò ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́. +Nígbà tí o bá kígbe,kí àwọn ère tí o kó jọ gbà ọ́.Atẹ́gùn lásán ni yóo gbé gbogbo wọn lọAfẹ́fẹ́ ni yóo fẹ́ wọn lọ.Ṣugbọn ẹni tí ó bá sá di mí,ni yóo ni ilẹ̀ náà,òun ni yóo sì jogún òkè mímọ́ mi. +OLUWA ní, “Ẹ la ọ̀nà, ẹ la ọ̀nà, ẹ tún ọ̀nà ṣe,ẹ mú gbogbo ohun ìkọsẹ̀ kúrò lọ́nà àwọn eniyan mi.” +Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ,ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́:òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́,ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀.Láti sọ ọkàn wọn jí. +Nítorí n kò ní máa jà títí ayé,tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo:nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde,Èmi ni mo dá èémí ìyè. +Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ojúkòkòrò rẹ̀, inú bí mi,mo jẹ ẹ́ níyà, mo fojú pamọ́, inú sì bí mi;sibẹ ó túbọ̀ ń ṣìnà sí i ni, ó ń ṣe tinú rẹ̀. +Mo ti rí bí ó ti ń ṣe,ṣugbọn n óo ṣì wò ó sàn;n óo máa darí rẹ̀, n óo tù ú ninu,n óo sì fún àwọn tí ó bá ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli ní orin ayọ̀. +Alaafia ni, alaafia ni fún àwọn tí ó wà ní òkèèrè, ati àwọn tí ó wà nítòsí;n óo sì wò wọ́n sàn. +Àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà òtítọ́, wọn óo wà ní alaafia,wọn óo máa sinmi lórí ibùsùn wọn. +Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú dàbí ríru omi òkun,nítorí òkun kò lè sinmi,omi rẹ̀ a sì máa rú pàǹtí ati ẹrẹ̀ sókè. +Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.” Ọlọrun mi ló sọ bẹ́ẹ̀. +Ẹ̀yin ọmọ oṣó wọnyi,ẹ súnmọ́bí fún ìdájọ́,ẹ̀yin ọmọ alágbèrè ati panṣaga. +Ta ni ẹ̀ ń fi ṣe ẹlẹ́yà?Ta ni ẹ̀ ń ya ẹnu ní ìyàkuyà sítí ẹ yọ ṣùtì sí?Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yínirú ọmọ ẹ̀tàn; +ẹ̀yin tí ẹ kún fún ìṣekúṣe lábẹ́ igi Oaku,ati lábẹ́ gbogbo igi eléwé tútù.Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ yín láàrin àfonífojì,ati ní abẹ́ àpáta? +Àwọn oriṣa láàrin àwọn òkúta ọ̀bọ̀rọ́, ninu àfonífojì,àwọn ni ẹ̀ ń sìn,àwọn ni ò ń da ẹbọ ohun mímu lé lórí,àwọn ni ò ń fi nǹkan jíjẹ rúbọ sí.Ṣé àwọn nǹkan wọnyi ni yóo mú kí inú mi yọ́? +Lórí òkè gíga fíofío, ni o lọ tẹ́ ibùsùn rẹ síníbẹ̀ ni o tí ń lọ rú ẹbọ. +O gbé ère oriṣa kalẹ̀ sí ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ati ẹ̀yìn òpó ìlẹ̀kùn.O kọ̀ mí sílẹ̀, o bọ́ sórí ibùsùn, o tẹ́ ibùsùn tí ó fẹ̀.O wá bá àwọn tí ó wù ọ́ da ọ̀rọ̀ pọ̀,ẹ̀ ń bá ara yín lòpọ̀. +O gbọ̀nà, o lọ gbé òróró fún oriṣa Moleki,o kó ọpọlọpọ turari lọ,o rán àwọn ikọ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,o sì ranṣẹ lọ sinu isà òkú pẹlu. +Ààwẹ̀ Tòótọ́. +“Kígbe sókè, má dákẹ́,ké sókè bíi fèrè ogun,sọ ìrékọjá àwọn eniyan mi fún wọn ní àsọyé,sọ ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jakọbu fún wọn. +Bí ẹ bá ṣe làálàá láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,tí ẹ sì wá ọ̀nà ìtẹ́lọ́rùn fún ẹni tí ìyà ń jẹ,ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn ninu òkùnkùn,òkùnkùn biribiri yín yóo dàbí ọ̀sán. +N óo máa tọ yín sọ́nà nígbà gbogbo,n óo fi nǹkan rere tẹ yín lọ́rùn;n óo mú kí egungun yín ó le,ẹ óo sì dàbí ọgbà tí à ń bomi rin,ati bí orísun omi, tí omi rẹ̀ kì í gbẹ. +Ẹ óo tún odi yín tí ó ti wó lulẹ̀ mọ,ẹ óo sì gbé àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dìde.Àwọn eniyan yóo máa pè yín ní alátùn-únṣe ibi tí odi ti wó,alátùn-únṣe òpópónà àdúgbò fún gbígbé. +“Bí ẹ bá dẹ́kun láti máa ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́,tí ẹ kò sì máa ṣe ìfẹ́ inú yín lọ́jọ́ mímọ́ mi;bí ẹ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ọjọ́ ìdùnnú,tí ẹ pe ọjọ́ mímọ́ OLUWA ní ọjọ́ ológo;bí ẹ bá yẹ́ ẹ sí, tí ẹ kò yà sí ọ̀nà tiyín,tí ẹ kò máa ṣe ìfẹ́ inú ara yín,tabi kí ẹ máa sọ̀rọ̀ àhesọ; +nígbà náà ni inú yín yóo máa dùn láti sin èmi OLUWA,n óo gbe yín gun orí òkè ilẹ̀ ayé,n óo sì mu yín jogún Jakọbu, baba ńlá yín.Èmi OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.” +Nítòótọ́ ni wọ́n ń wá mi lojoojumọ,wọ́n sì fẹ́ mọ ìlànà mi,wọ́n ṣe bí orílẹ̀-èdè tí ó mọ òdodo,tí kò kọ òfin Ọlọrun wọn sílẹ̀.Wọ́n ń bèèrè ìdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ mi,wọ́n ní ìfẹ́ ati súnmọ́ Ọlọrun.” +Wọ́n ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí à ń gbààwẹ̀, ṣugbọn tí OLUWA kò rí wa?Tí à ń fìyà jẹ ara wa, ṣugbọn tí kò náání wa?”OLUWA wí pé,“Ìdí rẹ̀ ni pé,nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ̀ máa ṣe ìfẹ́ ọkàn yín.Ẹ̀ sì máa ni gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ yín lára. +Ẹ̀ ń kún fún ìjà ati asọ̀ ní àkókò ààwẹ̀ yín,ẹ̀ ń lu ara yín ní ìlù ìkà.Irú ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà yìí kò ní jẹ́ kí Ọlọrun gbọ́ ohùn yín lọ́run. +Ṣé irú ààwẹ̀ tí mo yàn nìyí, ọjọ́ tí eniyan yóo rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lásán?Ṣé kí eniyan lè doríkodò bíi koríko etí odò nìkan ni?Tabi kí ó lè jókòó lórí aṣọ ọ̀fọ̀ ati eérú nìkan?Ṣé èyí ni ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀, ati ọjọ́ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA? +“Ṣebí irú ààwẹ̀ tí mo yàn ni pé:kí á tú ìdè ìwà burúkú,kí á yọ irin tí a fi di igi àjàgà;kí á dá àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́,kí á já gbogbo àjàgà? +Àní kí ẹ fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, kí ẹ mú àwọn òtòṣì aláìnílé wá sinu ilé yín,bí ẹ bá rí ẹnikẹ́ni ní ìhòòhò, kí ẹ fi aṣọ bò ó,kí ẹ má sì fojú pamọ́ fún ẹni tí ó jẹ́ ẹbí yín. +“Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn bí ìgbà tí ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́,ara yín yóo sì tètè yá.Òdodo yín yóo máa tàn níwájú yín.Ògo mi yóo ṣe ààbò lẹ́yìn yín. +Ẹ óo ké pè mí nígbà náà,n óo sì da yín lóhùn.Ẹ óo kígbe pè mí,n óo sì dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’“Bí ẹ bá mú àjàgà kúrò láàrin yín,tí ẹ kò fi ìka gún ara yín nímú mọ́,tí ẹ kò sì sọ ọ̀rọ̀ ibi mọ́. +Wolii Lòdì sí Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Eniyan. +Wò ó! Agbára OLUWA kò dínkù, tí ó fi lè gbani là,etí rẹ̀ kò di, tí kò fi ní gbọ́. +À ń táràrà lára ògiri bí afọ́jú,à ń táràrà bí ẹni tí kò lójú.À ń kọsẹ̀ lọ́sàn-án gangan,bí ẹni tí ó jáde ní àfẹ̀mọ́júmọ́a dàbí òkú láàrin àwọn alágbára. +Gbogbo wa ń bú bí ẹranko beari,a sì ń ké igbe ẹ̀dùn bí àdàbà.À ń retí ìdájọ́ òdodo, ṣugbọn kò sí;à ń retí ìgbàlà, ṣugbọn ó jìnnà sí wa. +“Nítorí àìdára wa pọ̀ níwájú rẹ,ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí lòdì sí wa;nítorí àwọn àìdára wa wà pẹlu wa,a sì mọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa: +A ń kọjá ààyè wa, à ń sẹ́ OLUWA,a sì ń yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun wa.Ọ̀rọ̀ ìninilára ati ọ̀tẹ̀ ni à ń sọ,èrò ẹ̀tàn ní ń bẹ lọ́kàn wa, ọ̀rọ̀ èké sì ní ń jáde lẹ́nu wa. +A fi ọwọ́ rọ́ ẹjọ́ ẹ̀tọ́ sẹ́yìn,òdodo sì takété.Òtítọ́ ti ṣubú ní gbangba ìdájọ́,ìdúróṣinṣin kò rọ́nà wọlé. +Òtítọ́ di ohun àwátì,ẹni tí ó yàgò fún iṣẹ́ ibi fi ara rẹ̀ fún ayé mú.”OLUWA rí i pé kò sí ìdájọ́ òdodo,ó sì bà á lọ́kàn jẹ́, +Ó rí i pé kò sí ẹnìkan tí yóo ṣe onílàjà, ẹnu sì yà á, pé kò sí ẹnìkankan.Ó bá fi ọwọ́ rẹ̀ ṣẹgun fún ara rẹ̀,òdodo rẹ̀ sì gbé e dúró. +Ó gbé òdodo wọ̀ bí ìgbàyà, ó fi àṣíborí ìgbàlà borí.Ó gbé ẹ̀san wọ̀ bí ẹ̀wù,ó fi bora bí aṣọ. +Yóo san ẹ̀san fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn,yóo bínú sí àwọn tí wọ́n lòdì sí i,yóo sì san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀,ati àwọn tí ń gbé erékùṣù. +Wọn óo bẹ̀rù orúkọ OLUWA láti ìwọ̀ oòrùn,wọn óo bẹ̀rù ògo rẹ̀ láti ìlà oòrùn;nítorí yóo wá bí ìkún omi, tí ẹ̀fúùfù láti ọ̀dọ̀ OLUWA ń taari. +Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó fa ìyapa láàrin ẹ̀yin ati Ọlọrun yín,àìdára yín ni ó mú kí ó fojú pamọ́ fun yín,tí kò fi gbọ́ ẹ̀bẹ̀ yín. +OLUWA ní, “N óo wá sí Sioni bí Olùràpadà, n óo wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Jakọbu,tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀. +“Majẹmu tí Èmi bá wọn dá nìyí: Ẹ̀mí mi tí mo fi le yín lórí, ati ọ̀rọ̀ mi tí mo fi si yín lẹ́nu, kò gbọdọ̀ kúrò lẹ́nu yín, ati lẹ́nu àwọn ọmọ rẹ, ati lẹ́nu arọmọdọmọ yín, láti àkókò yìí lọ ati títí laelae. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Ìpànìyàn ti sọ ọwọ́ yín di aláìmọ́,ọwọ́ yín kún fún ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀ ń purọ́,ẹ sì ń fi ẹnu yín sọ ọ̀rọ̀ burúkú. +Kò sí ẹni tí ó ń pe ẹjọ́ àre,kò sì sí ẹni tí ó ń rojọ́ òdodo.Ẹjọ́ òfo ni ẹ gbójú lé.Ẹ kún fún irọ́ pípa, ìkà ń bẹ ninu yín,iṣẹ́ burúkú sì ń bẹ lọ́wọ́ yín. +Ẹ̀ ń bá paramọ́lẹ̀ pa ẹyin rẹ̀,ẹ sì ń ran òwú aláǹtakùn,ẹni tí ó bá jẹ ninu ẹyin yín yóo kú.Bí ẹnìkan bá fọ́ ọ̀kan ninu ẹyin yín, ejò paramọ́lẹ̀ ni yóo jáde sí i. +Òwú aláǹtakùn yín kò lè di aṣọ,eniyan kò ní fi iṣẹ́ ọwọ́ yín bora.Iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni iṣẹ́ yín,ìwà ipá sì ń bẹ lọ́wọ́ yín. +Ẹsẹ̀ yín yá sí ọ̀nà ibi,ẹ sì yára sí àtipa aláìṣẹ̀.Èrò ẹ̀ṣẹ̀ ni èrò ọkàn yín.Ọ̀nà yín kún fún ìsọdahoro ati ìparun. +Ẹ kò mọ ọ̀nà alaafia, kò sí ìdájọ́ òdodo ní ọ̀nà yín.Ẹ ti mú kí ọ̀nà yín wọ́,ẹni tó bá ba yín rìn kò ní ní alaafia. +Àwọn eniyan bá dáhùn pé,“Nítorí náà ni ìdájọ́ òtítọ́ fi jìnnà sí wa,tí òdodo kò sì fi dé ọ̀dọ̀ wà.Ìmọ́lẹ̀ ni à ń retí, ṣugbọn òkùnkùn ló ṣú,ìtànṣán oòrùn ni à ń retí, ṣugbọn ìkùukùu ni ó bolẹ̀. +Ọlọrun Pe Aisaya láti jẹ́ Wolii. +Ní ọdún tí Usaya Ọba kú, mo rí OLUWA: ó jókòó lórí ìtẹ́, a gbé e ga sókè, aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. +Mú kí ọkàn àwọn eniyan wọnyi ó yigbì, jẹ́ kí etí wọn di.Fi nǹkan bò wọ́n lójú,kí wọn má baà ríran,kí wọn má sì gbọ́ràn,kí òye má baà yé wọn,kí wọn má baà yipada,kí wọn sì rí ìwòsàn.” +Mo bá bi í pé: “OLUWA mi, títí di ìgbà wo?”Ó sì dáhùn pé: “Títí tí àwọn ìlú yóo fi di ahoro, láìsí ẹni tí yóo máa gbé inú wọn; títí tí ilé yóo fi tú láì ku ẹnìkan, títí tí ilẹ̀ náà yóo fi di ahoro patapata. +Tí OLUWA yóo kó àwọn eniyan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tí ibi tí a kọ̀tì yóo sì di pupọ ní ilẹ̀ náà. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá àwọn eniyan náà ni ó kù ní ilẹ̀ náà, sibẹsibẹ iná yóo tún jó o bí igi terebinti tabi igi Oaku, tí kùkùté rẹ̀ wà lórí ilẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gé e lulẹ̀.”Èso mímọ́ ni kùkùté rẹ̀. +Àwọn Serafu dúró lókè rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ìyẹ́ mẹfa mẹfa: ó fi meji bo ojú, ó fi meji bo ẹsẹ̀, ó sì ń fi meji fò. +Ekinni ń ké sí ekeji pé:“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun;gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.” +Ìpìlẹ̀ ilé náà mì títí nígbà tí ẹni náà kígbe, èéfín sì kún ilé náà. +Mo bá pariwo, mo ní, “Mo gbé! Mo ti sọnù, nítorí pé ọ̀rọ̀ ẹnu mi kò mọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tí mò ń gbé ààrin wọn náà kò sì mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni mo ti fi ojú rí Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun.” +Ọ̀kan ninu àwọn Serafu náà bá fi ẹ̀mú mú ẹ̀yinná kan lórí pẹpẹ, ó mú un lọ́wọ́, ó bá fò wá sọ́dọ̀ mi. +Ó sì fi ògúnná náà kàn mí lẹ́nu, ó ní: “Wò ó, èyí ti kàn ọ́ ní ètè: A ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” +Mo wá gbọ́ ohùn OLUWA ó ní, “Ta ni kí n rán? Ta ni yóo lọ fún wa?”Mo bá dáhùn, mo ní: “Èmi nìyí, rán mi.” +OLUWA bá ní:“Lọ, sọ fún àwọn eniyan wọnyi pé;wọn óo gbọ́ títí, ṣugbọn kò ní yé wọn;wọn óo wò títí, ṣugbọn wọn kò ní rí nǹkankan. +Ògo Ọjọ́ Iwájú Jerusalẹmu. +Dìde, tan ìmọ́lẹ̀; nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,ògo OLUWA sì ti tàn sára rẹ. +OLUWA ní, “Àwọn àjèjì ni yóo máa tún odi rẹ mọ,àwọn ọba wọn yóo sì máa ṣe iranṣẹ fún ọ;nítorí pé inú ló bí mi ni mo fi nà ọ́.Ṣugbọn nítorí ojurere mi ni mo fi ṣàánú fún ọ. +Ṣíṣí ni ìlẹ̀kùn rẹ yóo máa wà nígbà gbogbo, a kò ní tì wọ́n tọ̀sán-tòru;kí àwọn eniyan lè máa kó ọrọ̀ orílẹ̀-èdè wá fún ọ,pẹlu àwọn ọba wọn tí wọn yóo máa tì siwaju. +Orílẹ̀-èdè tabi ilẹ̀ ọba tí kò bá sìn ọ́ yóo parun,wọn óo di àwópalẹ̀ patapata. +“Ògo Lẹbanoni yóo wá sí ọ̀dọ̀ rẹ:igi sipirẹsi, igi firi, ati igi pine;láti bukun ẹwà ilé mímọ́ mi,n óo sì ṣe ibi ìtìsẹ̀ mi lógo. +Àwọn ọmọ àwọn tí ń ni ọ́ lára yóo wá, wọn óo tẹríba fún ọ;gbogbo àwọn tí ń kẹ́gàn rẹ,yóo wá tẹríba lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ;wọn óo pè ọ́ ní ìlú OLÚWA,Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli. +“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ̀ ọ́,wọ́n sì kórìíra rẹ,tí kò sí ẹni tí ń gba ààrin rẹ̀ kọjá mọ́,n óo sọ ọ́ di àmúyangàn títí lae;àní, ohun ayọ̀ láti ìrandíran. +O óo mu wàrà àwọn orílẹ̀-èdè,o óo mu wàrà àwọn ọba.O óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni olùgbàlà rẹ,ati Olùràpadà rẹ, Ẹni Ńlá Jakọbu. +“Dípò bàbà, wúrà ni n óo mú wá.Dípò irin, fadaka ni n óo mú wá.Dípò igi, bàbà ni n óo mú wá.Dípò òkúta, irin ni n óo mú wá.N óo mú kí àwọn alabojuto yín wà ní alaafia,àwọn akóniṣiṣẹ́ yín yóo sì máa ṣe òdodo. +Kò tún ní sí ìró ìdàrúdàpọ̀ ní ilẹ̀ rẹ mọ́,kò sì ní sí ìdágìrì ati ìparun ní ibodè rẹ,o óo máa pe odi rẹ ní ìgbàlà,o óo sì máa pe ẹnubodè rẹ ní ìyìn. +“Kì í ṣe oòrùn ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe òṣùpá ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní òru:OLUWA ni yóo máa jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,Ọlọrun rẹ yóo sì jẹ́ ògo rẹ. +Nítorí òkùnkùn yóo bo ayé mọ́lẹ̀,òkùnkùn biribiri yóo sì bo àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ OLUWA yóo tàn sára rẹ,ògo OLUWA yóo sì hàn lára rẹ. +Oòrùn rẹ kò ní wọ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá rẹ kò ní wọ òkùnkùn.Nítorí OLUWA ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ yóo sì dópin. +Gbogbo àwọn eniyan rẹ yóo jẹ́ olódodo,àwọn ni yóo jogún ilẹ̀ náà títí lae.Àwọn ni ẹ̀ka igi tí mo gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi,kí á baà lè yìn mí lógo. +Ìdílé tí ó rẹ̀yìn jùlọ yóo di orílẹ̀-èdè,èyí tí ó sì kéré jùlọ yóo di orílẹ̀-èdè ńlá,Èmi ni OLUWA,kíákíá ni n óo ṣe é nígbà tí àkókò rẹ̀ bá tó.” +Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ,àwọn ọba yóo sì wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ tí ń tàn. +Gbé ojú sókè kí o wò yíká, gbogbo wọn kó ara wọn jọ, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ;àwọn ọmọ rẹ ọkunrin yóo wá láti òkèèrè,a óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin lé apá wá. +Nígbà tí o bá rí wọn,inú rẹ yóo dùn,ara rẹ óo yá gágá.Ọkàn rẹ yóo kún fún ayọ̀,nítorí pé a óo gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọrọ̀ inú òkun wá sọ́dọ̀ rẹ.Àwọn orílẹ̀-èdè yóo kó ọrọ̀ wọn wá fún ọ. +Ogunlọ́gọ̀ ràkúnmí yóo yí ọ ká,àwọn ọmọ ràkúnmí Midiani ati Efa.Gbogbo àwọn tí wọn wà ní Ṣeba yóo wá,wọn óo mú wúrà ati turari wá;wọn óo sì máa pòkìkí OLUWA. +Gbogbo ẹran ọ̀sìn Kedari ni wọ́n óo kó wá fún ọ,wọn óo kó àgbò Nebaiotu wá ta ọ́ lọ́rẹ.Wọn óo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi,ilé mi lógo, ṣugbọn n óo tún ṣe é lógo sí i. +Ta ni àwọn wọnyi tí ń fò lọ bí ìkùukùu?Bí ìgbà tí àwọn àdàbà bá ń fò lọ sí ibi ìtẹ́ wọn? +Nítorí àwọn erékùṣù yóo dúró dè mí,ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi ni yóo ṣiwajuwọn óo kó àwọn ọmọkunrin rẹ wá láti ilẹ̀ òkèèrè,wọn óo kó wúrà ati fadaka wá pẹlu wọn;nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ,ati Ẹni Mímọ́ Israẹli,nítorí ó ti ṣe ọ́ lógo. +Ìròyìn Ayọ̀ Ìdáǹdè. +Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi, nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí,láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára.Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu,kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn,kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n. +N óo máa yọ̀ ninu OLUWA, ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi.Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù,ó sì ti fi òdodo bòm�� lára bí aṣọ;bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì. +Bí ilẹ̀ tíí mú kí ewéko hù jáde,tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí a gbìn sinu rẹ̀ hù,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun yóo mú kí òdodo ati orin ìyìn yọ jádeníwájú gbogbo orílẹ̀-èdè. +Ó ní kí n máa kéde ọdún ojurere OLUWA, ati ọjọ́ ẹ̀san Ọlọrun wa;kí n sì máa tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ninu. +Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni,ní inú dídùn dípò ìkáàánú,kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́,kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo,tí OLUWA gbìn,kí á lè máa yìn ín lógo. +Wọn óo tún àlàpà ahoro àtijọ́ kọ́,wọn óo tún gbogbo ilé tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́,wọn óo sì tún ìlú tí a ti parun láti ọdún gbọọrọ kọ́. +Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín,àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín; +ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA,àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa.Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo. +Dípò ìtìjú ìpín tiyín yóo jẹ́ meji,dípò àbùkù ẹ óo láyọ̀ ninu ìpín tí ó kàn yín.Ìlọ́po meji ni ìpín yín yóo jẹ́ ninu ilẹ̀ yín,ayọ̀ ayérayé yóo sì jẹ́ tiyín. +OLUWA ní,“Nítorí pé mo fẹ́ ẹ̀tọ́,mo sì kórìíra ìfipá jalè ati ohun tí kò tọ́.Dájúdájú n óo san ẹ̀san fún wọn,n óo sì bá wọn dá majẹmu ayérayé. +Àwọn ọmọ wọn yóo dá yàtọ̀ láàrin orílẹ̀-èdè,a óo dá arọmọdọmọ wọn mọ̀ láàrin àwọn eniyan,gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn,yóo gbà pé èmi OLUWA ti bukun wọn.” +Nítorí Sioni, ń kò ní dákẹ́,nítorí Jerusalẹmu, ń kò ní sinmi,títí ìdáláre rẹ̀ yóo fi yọ bí ìmọ́lẹ̀,tí ìgbàlà rẹ̀ yóo sì tàn bí àtùpà. +Ẹ kọjá! Ẹ gba ẹnubodè kọjá,ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn eniyan.Ẹ la ọ̀nà, ẹ la òpópónà,kí ẹ ṣa òkúta kúrò níbẹ̀.Ẹ ta àsíá sókè, fún àwọn eniyan náà. +Wò ó! OLUWA ti kéde títí dé òpin ayé. Ó ní, “Ẹ sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé,‘Wò ó, olùgbàlà yín ti dé,èrè rẹ wà pẹlu rẹ̀,ẹ̀san rẹ sì wà níwájú rẹ̀.’ ” +A óo máa pè yín ní, “Eniyan mímọ́”,“Ẹni-Ìràpadà-OLUWA”.Wọn óo máa pè yín ní,“Àwọn-tí-a-wá-ní-àwárí”;wọn óo sì máa pe Jerusalẹmu ní,“Ìlú tí a kò patì”. +Àwọn orílẹ̀-èdè yóo rí ìdáláre rẹ,gbogbo ọba ni yóo rí ògo rẹ;orúkọ tuntun, tí OLUWA fúnra rẹ̀ yóo sọ ọ́,ni a óo máa pè ọ́. +O óo jẹ́ adé ẹwà lọ́wọ́ OLUWA,ati fìlà oyè lọ́wọ́ Ọlọrun rẹ. +A kò ní pè ọ́ ní “Ẹni-tí-a-kọ̀-sílẹ̀” mọ́,bẹ́ẹ̀ ni a kò ní pe ilẹ̀ rẹ ní “Ahoro” mọ́,“Ẹni-OLUWA-fẹ́” ni a óo máa pè ọ́,a óo máa pe ilẹ̀ rẹ ní “Ẹni-a-gbé-níyàwó.”Nítorí pé OLUWA nífẹ̀ẹ́ rẹ,ilẹ̀ rẹ yóo sì dàbí iyawo lójú rẹ̀. +Bí ọdọmọkunrin tií nífẹ̀ẹ́ wundia,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkunrin rẹ yóo nífẹ̀ẹ́ rẹ.Bí inú ọkọ iyawo tuntun tíí dùn nítorí iyawo rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọrun rẹ yóo dùn nítorí rẹ. +Jerusalẹmu, mo ti fi àwọn aṣọ́de sí orí odi rẹ;lojoojumọ, tọ̀sán-tòru, wọn kò gbọdọ̀ panumọ́.Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rán OLUWA létí,ẹ má dákẹ́. +Ẹ má jẹ́ kí ó sinmi,títí yóo fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀,títí yóo fi sọ ọ́ di ìlú ìyìn láàrin gbogbo ayé. +OLUWA ti fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ búra,ó ti fi agbára rẹ̀ jẹ́ ẹ̀jẹ́,pé òun kò ní fi ọkà oko rẹ,ṣe oúnjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ mọ́;àwọn àjèjì kò sì ní mu ọtí waini rẹ,tí o ṣe wahala lé lórí mọ́. +Ṣugbọn àwọn tí ó bá gbin ọkà, ni yóo máa jẹ ẹ́,wọn óo sì máa fìyìn fún OLUWA;àwọn tí ó bá sì kórè àjàrà ni yóo mu ọtí rẹ̀,ninu àgbàlá ilé mímọ́ mi. +Ìṣẹ́gun OLUWA lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè. +“Ta ni ń ti Edomu bọ̀ yìí,tí ó wọ aṣọ àlàárì, tí ń bọ̀ láti Bosira,tí ó yọ bí ọjọ́ ninu aṣọ tí ó wọ̀,tí ń yan bọ̀ ninu agbára ńlá rẹ̀.”“Èmi ni, èmi tí mò ń kéde ẹ̀san,tí mo sì lágbára láti gbani là.” +Ṣugbọn wọ́n hùwà ọlọ̀tẹ̀:wọ́n sì mú Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ bínú.Nítorí náà ó di ọ̀tá wọn,ó sì dojú ìjà kọ wọ́n. +Ṣugbọn ó ranti ìgbà àtijọ́,ní àkókò Mose, iranṣẹ rẹ̀.Wọ́n bèèrè pé,ẹni tí ó kó wọn la òkun já dà?Olùṣọ́-aguntan agbo rẹ̀,tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn? +Ẹni tí ó gbé agbára rẹ̀ tí ó lógo wọ Mose, tí ó pín òkun níyà níwájú wọn,kí orúkọ rẹ̀ lè lókìkí títí lae. +Ó mú wọn la ibú omi kọjá, bí ẹṣin ninu aṣálẹ̀;wọ́n rìn, wọn kò fẹsẹ̀ kọ. +Wọ́n rìn wọnú àfonífojì bíi mààlúù,Ẹ̀mí OLUWA sì fún wọn ní ìsinmi.Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe darí àwọn eniyan rẹ̀,kí ó lè gba ògo fún orúkọ rẹ̀. +Bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run,láti ibùgbé rẹ mímọ́ tí ó lógo.Ìtara rẹ dà? Agbára rẹ dà?O ti dáwọ́ ìfẹ́ ati àánú rẹ dúró lára wa ni? +Ìwọ ni baba wa.Bí Abrahamu kò tilẹ̀ mọ̀ wá,tí Israẹli kò sì dá wa mọ̀.Ìwọ OLUWA ni baba wa,Olùràpadà wa láti ìgbà àtijọ́, ni orúkọ rẹ. +OLUWA kí ló dé tí o fi jẹ́ kí á ṣìnà, kúrò lọ́dọ̀ rẹ;tí o sé ọkàn wa lé, tí a kò fi bẹ̀rù rẹ?Pada sọ́dọ̀ wa nítorí àwọn iranṣẹ rẹ,nítorí àwọn ẹ̀yà Israẹli tíí ṣe ìní rẹ. +Fún ìgbà díẹ̀, ilé mímọ́ rẹ jẹ́ ti àwa eniyan mímọ́ rẹ;ṣugbọn àwọn ọ̀tá wa ti wó o lulẹ̀. +A wá dàbí àwọn tí o kò jọba lórí wọn rí,àní, bí àwọn tí a kò fi orúkọ rẹ pè. +“Kí ló dé tí aṣọ rẹ fi pupa,tí ó dàbí ti ẹni tí ń fún ọtí waini?” +OLUWA dáhùn, ó ní, “Èmi nìkan ni mo tí ń fún ọtí waini, ẹnikẹ́ni kò bá mi fún un ninu àwọn eniyan mi.Mo fi ibinu tẹ̀ wọ́n bí èso àjàrà,mo fi ìrúnú tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.Ẹ̀jẹ̀ wọn bá dà sí mi láṣọ:ó ti di àbààwọ́n sára gbogbo aṣọ mi. +Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ló wà lọ́kàn mi,ọdún ìràpadà mi sì ti dé. +Mo wò yíká, ṣugbọn kò sí olùrànlọ́wọ́, ẹnu yà mí pé, n kò rí ẹnìkan tí yóo gbé mi ró;nítorí náà, agbára mi ni mo fi ṣẹgun,ibinu mi ni ó sì gbé mi ró. +Mo fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀, mo fi ìrúnú rọ wọ́n yó,mo sì tú ẹ̀jẹ̀ wọn dà sílẹ̀.” +N óo máa sọ nípa ìfẹ́ ńlá OLUWA lemọ́lemọ́,n óo máa kọrin ìyìn rẹ̀;nítorí gbogbo ohun tí OLUWA ti fún wa,ati oore ńlá tí ó ṣe fún ilé Israẹli,tí ó ṣe fún wọn nítorí àánú rẹ̀,ati gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀. +OLUWA ní, “Dájúdájú eniyan mi mà ni wọ́n,àwọn ọmọ tí kò ní hùwà àgàbàgebè.”Ó sì di Olùgbàlà wọn. +Ninu gbogbo ìyà tí wọ́n jẹ, òun pẹlu wọn ni,angẹli iwájú rẹ̀ sì gbà wọ́n là.Nítorí ìfẹ́ ati àánú rẹ̀, ó rà wọ́n pada.Ó fà wọ́n sókè, ó sì gbé wọn ní gbogbo ìgbà àtijọ́. +Ò bá jẹ́ fa awọsanma ya kí o sì sọ̀kalẹ̀,kí àwọn òkè ńlá máa mì tìtì níwájú rẹ; +Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀,Sioni ti di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu sì ti di ahoro. +Wọ́n ti dáná sun ilé mímọ́ wa tí ó lẹ́wà,níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,gbogbo ibi dáradára tí a ní, ló ti di ahoro. +OLUWA, ṣé o kò ní ṣe nǹkankan sí ọ̀rọ̀ yìí ni?Ṣé o óo dákẹ́, o óo máa fìyà jẹ wá ni? +bí ìgbà tí iná ń jó igbó ṣúúrú,tí iná sì ń mú kí omi hó.Kí orúkọ rẹ di mímọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ,kí àwọn orílẹ̀-èdè lè máa gbọ̀n níwájú rẹ! +Nígbà tí o bá ṣe nǹkan tí ó bani lẹ́rù,tí ẹnikẹ́ni kò retí,o sọ̀kalẹ̀, àwọn òkè ńlá sì mì tìtì níwájú rẹ. +Láti ìgbà àtijọ́, ẹnìkan kò gbọ́ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò tíì fi ojú rí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ,tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e. +Ò máa ran àwọn tí ń fi inú dídùn ṣiṣẹ́ òdodo lọ́wọ́,àwọn tí wọn ranti rẹ ninu ìgbé ayé wọn,o bínú, nítorí náà a dẹ́ṣẹ̀,a ti wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa tipẹ́.Ǹjẹ́ a óo rí ìgbàlà? +Gbogbo wa dàbí aláìmọ́,gbogbo iṣẹ́ òdodo wa dàbí àkísà ẹlẹ́gbin.Gbogbo wa rọ bí ewé,àìdára wa sì ń fẹ́ wa lọ bí atẹ́gùn. +Kò sí ẹnìkan tí ń gbadura ní orúkọ rẹ,kò sí ẹni tí ń ta ṣàṣà láti dìmọ́ ọ;nítorí pé o ti fojú pamọ́ fún wa,o sì ti pa wá tì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. +Sibẹsibẹ OLUWA, ìwọ ni baba wa,amọ̀ ni wá, ìwọ sì ni amọ̀kòkò;iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni gbogbo wa. +OLUWA má bínú pupọ jù,má máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wa títí lae.Jọ̀wọ́, ro ọ̀rọ̀ wa wò,nítorí pé eniyan rẹ ni gbogbo wa. +Ìyà tí Ọlọrun yóo fi Jẹ Àwọn Ọlọ̀tẹ̀. +Mo ṣetán láti mú kí àwọn tí kò bèèrè mi máa wá mi, ati láti fi ara mi han àwọn tí kò wá mi.Mo sọ fún orílẹ̀-èdè tí kì í gbadura ní orúkọ mi pé,“Èmi nìyí, èmi nìyí.” +Ilé Ṣaroni yóo di ibùjẹ ẹran, àfonífojì Akori yóo sì di ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo máa dùbúlẹ̀ sí,fún àwọn eniyan mi, tí wọ́n wá mi. +“Ṣugbọn níti ẹ̀yin tí ẹ kọ mí sílẹ̀,tí ẹ gbàgbé Òkè Mímọ́ mi,tí ẹ tẹ́ tabili sílẹ̀ fún Gadi, oriṣa Oríire,tí ẹ̀ ń po àdàlú ọtí fún Mẹni, oriṣa Àyànmọ́. +N óo fi yín fún ogun pa,gbogbo yín ni ẹ óo sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn apànìyàn;nítorí pé nígbà tí mo pè yín, ẹ kò dáhùn,nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹ kò gbọ́,ẹ ṣe nǹkan tí ó burú lójú mi;ẹ yan ohun tí inú mi kò dùn sí. +Wò ó, àwọn iranṣẹ mi yóo máa rí oúnjẹ jẹ,ṣugbọn ebi yóo máa pa yín;àwọn iranṣẹ mi yóo mu waini,ṣugbọn òùngbẹ yóo máa gbẹ yín.Àwọn iranṣẹ mi yóo máa yọ̀,ṣugbọn ìtìjú yóo máa ba yín. +Àwọn iranṣẹ mi yóo máa kọrin nítorí inú wọn dùn,ṣugbọn ẹ̀yin óo máa kígbe oró àtọkànwá;ẹ óo sì máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí àròkàn. +Orúkọ tí ẹ óo fi sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ miyóo di ohun tí wọn yóo máa fi gégùn-ún.Èmi Oluwa Ọlọrun óo pa yín.Ṣugbọn n óo pe àwọn iranṣẹ mi ní orúkọ mìíràn. +Dé ibi pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ tọrọ ibukun ní ilẹ̀ náà,yóo máa tọrọ rẹ̀ ní orúkọ Ọlọrun òtítọ́,ẹnikẹ́ni tí yóo bá sì búra ní ilẹ̀ náà,orúkọ Ọlọrun òtítọ́ ni yóo máa fi búra.Àwọn ìṣòro àtijọ́ yóo ti di ohun ìgbàgbé,a óo sì ti fi wọ́n pamọ́ kúrò níwájú mi.” +OLUWA ní, “Mo dá ọ̀run tuntun, ati ayé tuntun;a kò ní ranti àwọn ohun àtijọ́ mọ́,tabi kí wọn sọ sí eniyan lọ́kàn. +Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí inú yín ó máa dùn,kí ẹ sì máa yọ títí lae, ninu ohun tí mo dá.Wò ó! Mo dá Jerusalẹmu ní ìlú aláyọ̀,mo sì dá àwọn eniyan inú rẹ̀ ní onínú dídùn. +N óo láyọ̀ ninu Jerusalẹmu,inú mi óo sì máa dùn sí àwọn eniyan mi.A kò ní gbọ́ igbe ẹkún ninu rẹ̀ mọ́,ẹnikẹ́ni kò sì ní sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ninu rẹ̀ mọ́. +Láti òwúrọ̀ di alẹ́, mo na ọwọ́ mi sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ eniyan; àwọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà tí kò dára,tí wọn ń tẹ̀lé èrò ọkàn wọn, +Ọmọ tuntun kò ní kú ní Jerusalẹmu mọ́,àwọn àgbààgbà kò sì ní kú láìjẹ́ pé wọ́n darúgbó kùjọ́kùjọ́.Kàkà bẹ́ẹ̀, ikú ọ̀dọ́ ni a óo máa pe ikú ẹni tí ó bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún.Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún,a óo sọ pé ó kú ikú ègún. +Wọn óo kọ́ ilé, wọn óo gbé inú rẹ̀;wọn óo gbin ọgbà àjàrà, wọn óo sì jẹ èso rẹ̀. +Wọn kò ní kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé,wọn kò sì ní gbin ọgbà àjàrà fún ẹlòmíràn jẹ.Àwọn eniyan mi yóo pẹ́ láyé bí igi ìrókò,àwọn àyànfẹ́ mi yóo sì jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn. +Wọn kò ní ṣe iṣẹ́ àṣedànù,wọn kò ní bímọ fún jamba;nítorí ọmọ ẹni tí OLUWA bukun ni wọn yóo jẹ́,àwọn ati àwọn ọmọ wọn. +Kí wọn tó pè mí, n óo ti dá wọn lóhùn,kí wọn tó sọ̀rọ̀ tán, n óo ti gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ. +Ìkookò ati ọmọ aguntan yóo jọ máa jẹ káàkiri; kinniun yóo máa jẹ koríko bíi mààlúù,erùpẹ̀ ni ejò yóo máa jẹ, wọn kò ní máa panilára.Wọn kò sì ní máa panirun lórí òkè mímọ́ mi mọ́.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +tí wọn ń ṣe ohun tí yóo mú mi bínú,níṣojú mi, nígbà gbogbo.Wọ́n ń rúbọ ninu oríṣìíríṣìí ọgbà,wọ́n ń sun turari lórí bíríkì. +Àwọn tí wọn ń jókòó sí itẹ́ òkú,tí wọn ń dúró níbi ìkọ̀kọ̀ lóru;àwọn tí wọn ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,tí ìṣaasùn ọbẹ̀ wọn sì kún fún ẹran aláìmọ́. +Wọn á máa ké pé, “Yàgò lọ́nà. Má fara kàn mí,nítorí mo jẹ́ ẹni mímọ́ jù ọ́ lọ.”Ṣugbọn bí èéfín ni irú wọn rí ní ihò imú mi,bí iná tí ó ń jó lojoojumọ. +Wò ó! A ti kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú mi pé,“N kò ní dákẹ́, ṣugbọn n óo gbẹ̀san. +N óo gbẹ̀san gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lára wọn,ati ti àwọn baba wọn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Nítorí pé wọ́n ń sun turari lórí àwọn òkè ńlá,wọ́n sì ń fi mí ṣẹ̀sín lórí àwọn òkè kéékèèké.N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn àtẹ̀yìnwá fún wọn. +“Bí eniyan tíí wòye pé ọtí wà lára ìdì èso àjàrà,tí wọn sìí sọ pé, ‘Ẹ má bà á jẹ́,nítorí ohun rere wà ninu rẹ̀,’bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe nítorí iranṣẹ mi,n kò ní pa gbogbo wọn run. +N óo mú kí arọmọdọmọ jáde lára Jakọbu,àwọn tí yóo jogún òkè ńlá mi yóo sì jáde láti ara Juda.Àwọn tí mo ti yàn ni yóo jogún rẹ̀,àwọn iranṣẹ mi ni yóo sì máa gbé ibẹ̀. +OLUWA Dá àwọn Orílẹ̀-Èdè Lẹ́jọ́. +OLUWA ní: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.Ilé tí ẹ kọ́ fún mi dà?Níbo sì ni ibi ìsinmi mi wà? +Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀, kí inú yín dùn nítorí rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀,ẹ bá a yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ nítorí rẹ̀. +Kí ẹ lè mu àmutẹ́rùn, ninu wàrà rẹ̀ tí ń tuni ninu;kí ẹ lè ní ànítẹ́rùn pẹlu ìdùnnú,ninu ọpọlọp��� ògo rẹ̀. +Nítorí OLUWA ní:“N óo tú ibukun sórí rẹ̀,bí ìgbà tí odò bá ń ṣàn.N óo da ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,bí odò tí ò ṣàn kọjá bèbè.Yóo dà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí ọmọ tí ń mu ọmú,ẹ óo máa ṣeré lórí orúnkún rẹ̀. +N óo rẹ̀ yín lẹ́kún bí ọmọ tí ìyá rẹ̀ rẹ̀ lẹ́kún,bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tù yín ninu ní Jerusalẹmu. +Ẹ óo rí i, inú yín yóo dùn, egungun yín yóo sọjí,bí ìgbà tí koríko bá rúwé.Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé ọwọ́ OLUWA wà lára àwọn iranṣẹ rẹ̀,ati pé inú bí i sí àwọn ọ̀tá rẹ̀.” +Wò ó! OLUWA ń bọ̀ ninu iná,kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo dàbí ìjì,láti fi ìrúnú san ẹ̀san,yóo sì fi ahọ́n iná báni wí. +Nítorí pé iná ni OLUWA yóo fi ṣe ìdájọ́,idà ni yóo fi ṣe ìdájọ́ fún gbogbo eniyan;àwọn tí OLUWA yóo fi idà pa yóo sì pọ̀. +OLUWA ní, “Àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀, tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n ń lọ bọ̀rìṣà ninu àgbàlá, wọ́n ń jó ijó oriṣa, wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀, ati àwọn ohun ìríra, ati èkúté! Gbogbo wọn ni yóo ṣègbé papọ̀. +Nítorí mo mọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn ati èrò ọkàn wọn. Mò ń bọ̀ wá gbá gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà jọ. Nígbà tí wọ́n bá dé, wọ́n óo rí ògo mi. +“N óo sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn. N óo rán àwọn tí ó yè lára wọn sí àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn bíi: Taṣiṣi, Puti, ati Ludi, ilẹ̀ àwọn tafàtafà, ati Tubali ati Jafani, ati àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré; àwọn tí kò tíì gbọ́ òkìkí mi, tí wọn kò sì tíì rí ògo mi rí. Wọn óo sì ròyìn ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. +Ọwọ́ mi ni mo fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi, tèmi sì ni gbogbo wọn.Ẹni tí n óo kà kún,ni onírẹ̀lẹ̀ ati oníròbìnújẹ́ eniyan, tí ó ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ mi. +Wọn óo sì kó gbogbo àwọn ará yín bọ̀ láti orílẹ̀-èdè gbogbo, wọn óo kó wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA. Wọn óo máa bọ̀ lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́-ogun, lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí, wọn óo máa wá sí ìlú Jerusalẹmu, òkè mímọ́ mi, bí àwọn ọmọ Israẹli yóo ti máa mú ẹbọ ohun jíjẹ wọn wá sí ilé OLUWA, ninu àwo tí ó mọ́. +N óo mú ninu wọn, n óo fi ṣe alufaa ati ọmọ Lefi. +“Bí ọ̀run tuntun ati ayé tuntun tí n óo dá, yóo ṣe máa wà níwájú mi, bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ ati orúkọ rẹ̀ yóo máa wà. +Láti oṣù tuntun dé oṣù tuntun, ati láti ọjọ́ ìsinmi kan dé ekeji, ni gbogbo eniyan yóo máa wá jọ́sìn níwájú mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Wọn óo jáde, wọn óo sì fojú rí òkú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí mi; nítorí ìdin tí ń jẹ wọ́n kò ní kú, bẹ́ẹ̀ ni iná tí ń jó wọn kò ní kú; wọn óo sì jẹ́ ohun ìríra lójú gbogbo eniyan.” +“Ati ẹni tí ó pa mààlúù rúbọ,ati ẹni tí ó pa eniyan;kò sí ìyàtọ̀.Ẹni tí ó fi ọ̀dọ́ aguntan rúbọ,kò yàtọ̀ sí ẹni tí ó lọ́ ajá lọ́rùn pa.Ati ẹni tí ó fi ọkà rúbọ,ati ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ,bákan náà ni wọ́n rí.Ẹni tí ó fi turari ṣe ẹbọ ìrántí,kò sì yàtọ̀ sí ẹni tí ó súre níwájú oriṣa.Wọ́n ti yan ọ̀nà tí ó wù wọ́n,wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn sin ohun ìríra wọn. +Èmi náà óo sì yan ìjìyà fún wọn,n óo jẹ́ kí ẹ̀rù wọn pada sórí wọn.Nítorí pé nígbà tí mo pè wọ́n, ẹnikẹ́ni wọn kò dáhùn;nígbà tí mo sọ̀rọ̀ fún wọn, wọn kò gbọ́,wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú mi,wọ́n yan ohun tí inú mi kò dùn sí.” +Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀:“Àwọn arakunrin yín tí wọn kórìíra yín,wọ́n tì yín síta nítorí orúkọ mi;wọ́n ní, ‘Jẹ́ kí OLUWA fi ògo rẹ̀ hàn,kí á lè rí ayọ̀ yín.’Ṣugbọn àwọn ni ojú yóo tì. +Ẹ gbọ́ ariwo ninu ìlú,ẹ gbọ́ ohùn kan láti inú Tẹmpili,ohùn OLUWA ni,ó ń san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. +“Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ó ti bímọ. Kí ìrora obí tó mú un,ó ti bí ọmọkunrin kan. +Ta ló gbọ́ irú èyí rí?Ta ló rí irú rẹ̀ rí?Ǹjẹ́ a lè bí ilẹ̀ ní ọjọ́ kan,tabi kí á bí orílẹ̀-èdè kan ní ọjọ́ kan?Ní kété tí Sioni bẹ̀rẹ̀ sí rọbí,ni ó bí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin. +Ṣé mo lè jẹ́ kí eniyan máa rọbí,kí n má jẹ́ kí ó bímọ bí?Èmi OLUWA, tí mò ń mú kí eniyan máa bímọ,ṣé, mo jẹ́ sé eniyan ninu?” +Aisaya Jíṣẹ́ OLUWA fún Ahasi Ọba. +Nígbà ayé Ahasi, ọmọ Jotamu, ọmọ Usaya, ọba Juda, Resini Ọba Siria ati Peka ọmọ Remalaya, ọba Israẹli wá gbé ogun ti Jerusalẹmu, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀. +OLUWA tún sọ fún Ahasi pé: +“Bèèrè àmì tí ó bá wù ọ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun rẹ–ìbáà jìn bí isà òkú, tabi kí ó ga bí ojú ọ̀run.” +Ṣugbọn Ahasi dáhùn, ó ní: “Èmi kò ní bèèrè nǹkankan, n kò ní dán OLUWA wò.” +Aisaya bá dáhùn pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Dafidi, ṣé eniyan tí ẹ̀ ń yọ lẹ́nu kò to yín, Ọlọrun mi alára lókù tí ẹ tún ń yọ lẹ́nu? +Nítorí náà, OLUWA fúnrarẹ̀ yóo fun yín ní àmì kan. Ẹ gbọ́! Ọlọ́mọge kan yóo lóyún yóo sì bí ọmọkunrin kan, yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli. +Nígbà tí yóo bá fi mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú, tí a sì í yan nǹkan rere, wàrà ati oyin ni àwọn eniyan yóo máa jẹ. +Nítorí pé kí ọmọ náà tó mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú tí a sì í yan nǹkan rere, ilẹ̀ àwọn ọba mejeeji tí wọn ń bà ọ́ lẹ́rù yìí yóo ti di ìkọ̀sílẹ̀. +“OLUWA yóo mú ọjọ́ burúkú dé bá ìwọ ati àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ, ọjọ́ tí kò ì tíì sí irú rẹ̀ rí, láti ìgbà tí Efuraimu ti ya kúrò lára Juda, OLUWA ń mú ọba Asiria bọ̀. +“Ní ọjọ́ náà OLUWA yóo súfèé pe àwọn eṣinṣin tí ó wà ní orísun gbogbo odò Ijipti ati àwọn oyin tí ó wà ní ilẹ̀ Asiria. +Gbogbo wọn yóo sì rọ́ wá sí ààrin àwọn àfonífojì, ati gbogbo kọ̀rọ̀ kọ̀rọ̀ ní ààrin àpáta, ati ara gbogbo igi ẹlẹ́gùn-ún ati gbogbo pápá. +Nígbà tí ìròyìn dé ilé ọba Dafidi pé àwọn ará Siria ati Efuraimu ń gbógun bọ̀, ọkàn òun ati àwọn eniyan rẹ̀ mì tìtì bí afẹ́fẹ́ tíí mi igi ninu igbó. +“Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo mú ọba Asiria wá láti òdìkejì odò. Yóo lò ó bí abẹ ìfárí, yóo fi fá irun orí ati irun ẹsẹ̀ dànù, ati gbogbo irùngbọ̀n pàápàá. +“Ní ọjọ́ náà, eniyan yóo máa sin ẹyọ mààlúù kékeré kan ati aguntan meji péré, +wàrà tí yóo máa rí fún yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé wàrà ati oyin ni yóo máa fi ṣe oúnjẹ jẹ. Nítorí pé wàrà ati oyin ni àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà yóo máa jẹ. +“Ní ọjọ́ náà, gbogbo ibi tí ẹgbẹrun ìtàkùn àjàrà wà, tí owó rẹ̀ tó ẹgbẹrun ṣekeli fadaka, yóo di igbó ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn. +Àwọn eniyan yóo kó ọrun ati ọfà wá sibẹ, nítorí gbogbo ilẹ̀ náà yóo di igbó ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn. +Gbogbo ara òkè tí wọn tí ń fi ọkọ́ ro tẹ́lẹ̀, ẹnikẹ́ni kò ní lè débẹ̀ mọ́, nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn, gbogbo ibẹ̀ yóo wá di ibi tí mààlúù ati aguntan yóo ti máa jẹko.” +OLUWA sọ fún Aisaya pé, “Lọ bá Ahasi, ìwọ ati Ṣeari Jaṣubu, ọmọ rẹ, ní òpin ibi tí wọ́n fa omi dé ní ọ̀nà àwọn alágbàfọ̀. +Kí o sọ fún un pé, ṣọ́ra, farabalẹ̀, má sì bẹ̀rù. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ já rárá nítorí ibinu gbígbóná Resini ati Siria, ati ti ọmọ Remalaya, nítorí wọn kò yàtọ̀ sí àjókù igi iná meji tí ń rú èéfín. +Nítorí pé Siria, pẹlu Efuraimu ati ọmọ Remalaya ti pète ati ṣe ọ́ ní ibi. Wọ́n ń sọ pé, +‘Ẹ jẹ́ kí á lọ gbógun ti Juda, kí á dẹ́rùbà á, ẹ jẹ́ kí á ṣẹgun rẹ̀ kí á sì gbà á, kí á fi ọmọ Tabeeli jọba lórí rẹ̀!’ +“Àbá tí wọn ń dá kò ní ṣẹ, ète tí wọn ń pa kò ní rí bẹ́ẹ̀. +Ṣebí Damasku ni olú-ìlú Siria, Resini sì ni olórí Damasku. Láàrin ìsinyìí sí ọdún marundinlaadọrin, Efuraimu yóo fọ́nká, kò sì ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́. +Ṣebí Samaria ni olú-ìlú Efuraimu, Ọmọ Remalaya sì ni olórí Samaria. Bí ẹ kò bá gbàgbọ́ ẹ kò ní fẹsẹ̀ múlẹ̀.” +Ọmọ Aisaya jẹ́ Àmì fún Àwọn Eniyan. +Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún mi pé, “Mú ìwé kan tí ó fẹ̀, kí o kọ Maheriṣalali-haṣi-basi sí i lórí gàdàgbà gàdàgbà.” +Bí ẹ gbìmọ̀ pọ̀ ìmọ̀ yín yóo di òfo.Ohun yòówù tí ẹ lè sọ, àpérò yín yóo di asán.Nítorí pé Ọlọrun wà pẹlu wa. +Nítorí ọwọ́ agbára ni OLUWA fi lé mi lára, nígbà tí ó ń sọ èyí fún mi. Ó sì ti kìlọ̀ fún mi pé kí n má bá àwọn eniyan wọnyi rìn, ó ní, +“Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ tí àwọn eniyan yìí ń dì. Bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bẹ̀rù ohun tí wọn ń bẹ̀rù. +OLUWA àwọn ọmọ ogun nìkan ni kí o kà sí mímọ́, òun ni kí ẹ̀rù rẹ̀ máa bà ọ́. Òun nìkan ni kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa pá ọ láyà. +Yóo di ibi-mímọ́ ati òkúta ìdìgbòlù, ati àpáta tí ó ń mú kí eniyan kọsẹ̀, fún ilẹ̀ Israẹli mejeeji. Yóo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fún àwọn ará Jerusalẹmu. +Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo kọsẹ̀ níbẹ̀; wọn yóo ṣubú, wọn yóo sì fọ́ wẹ́wẹ́. Tàkúté yóo mú wọn, ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.” +Di ẹ̀rí náà, fi èdìdì di ẹ̀kọ́ náà láàrin àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi. +N óo dúró de OLUWA ẹni tí ó fojú pamọ́ fún ilé Jakọbu, n óo sì ní ìrètí ninu rẹ̀. +Ẹ wò ó! Èmi ati àwọn ọmọ tí OLUWA fún mi, a wà fún àmì ati ìyanu ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ń gbé orí òkè Sioni. +Nígbà tí wọ́n bá wí fun yín pé kí ẹ lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn àjẹ́ ati àwọn abókùúsọ̀rọ̀ tí wọn ń jẹ ẹnu wúyẹ́-wúyẹ́. Ṣé kò yẹ kí orílẹ̀-èdè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun wọn? Ṣé lọ́dọ̀ òkú ni ó ti yẹ kí alààyè ti máa wádìí ọ̀rọ̀? +Mo bá pe Alufaa Uraya ati Sakaraya, ọmọ Jebẹrẹkaya, kí wọn wá ṣe ẹlẹ́rìí mi nítorí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. +Ẹ lọ wádìí ninu ẹ̀kọ́ mímọ́ ati ẹ̀rí. Bí ẹnìkan bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí, kò sí òye ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀. +Wọn yóo kọjá lọ lórí ilẹ̀ náà ninu ìnira ati ebi; nígbà tí ebi bá pa wọ́n, wọn yóo máa kanra, wọn óo gbé ojú wọn sókè, wọn óo sì gbé ọba ati Ọlọrun wọn ṣépè. +Wọn óo bojú wo ilẹ̀, kìkì ìdààmú ati òkùnkùn ati ìṣúdudu ati ìnira ni wọn óo rí. A óo sì sọ wọ́n sinu òkùnkùn biribiri. +Nígbà tí mo bá iyawo mi, tí òun náà jẹ́ wolii lò pọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin. OLUWA bá sọ fún mi pé kí n sọ ọmọ náà ní Maheriṣalali-haṣi-basi. +Nítorí kí ọmọ náà tó mọ bí a tí ń pe ‘Baba mi’ tabi ‘Mama mi’, wọn óo ti kó àwọn nǹkan alumọni Damasku ati ìkógun Samaria lọ sí Asiria. +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀ ó ní, +“Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi kọ omi Ṣiloa tí ń ṣàn wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ sílẹ̀, wọ́n wá ń gbọ̀n jìnnìjìnnì níwájú Resini ati ọmọ Remalaya, +nítorí náà, ẹ wò ó, OLUWA yóo gbé ọba Asiria ati gbogbo ògo rẹ̀ dìde wá bá wọn, yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí omi odò Yufurate, tí ó kún àkúnya, tí ó sì kọjá bèbè rẹ̀. +Yóo ya wọ Juda, yóo sì bò ó mọ́lẹ̀ bí ó ti ń ṣàn kọjá lọ, títí yóo fi mù ún dé ọrùn. Yóo ya wọ inú ilẹ̀ rẹ̀ látòkè délẹ̀; yóo sì bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀. Kí Ọlọrun wà pẹlu wa.” +Ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ kó ara yín jọ!A óo fọ yín túútúú.Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè.Ẹ di ara yín ní àmùrè;a óo fọ yín túútúú.Ẹ di ara yín ní àmùrè,a óo fọ yín túútúú. +Ọba Lọ́la. +Ṣugbọn kò ní sí ìṣúdudu fún ẹni tí ó wà ninu ìnira. Ní ìgbà àtijọ́, ó sọ ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali di yẹpẹrẹ, ṣugbọn nígbà ìkẹyìn yóo ṣe ilẹ̀ àwọn tí ó ń gbé apá ọ̀nà òkun lógo, títí lọ dé òdìkejì odò Jọdani, ati Galili níbi tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé. +Ṣé bíríkì ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé tí ó wó lulẹ̀?Òkúta gbígbẹ́ ni a óo fi tún wọn kọ́.Igi sikamore ni a fi kọ́ èyí tí wọ́n dà wó,ṣugbọn igi kedari dáradára ni a óo lò dípò wọn. +Nítorí náà OLUWA ti gbé ọ̀tá dìde sí wọn:Ó ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè sí wọn: +Àwọn ará Siria láti ìhà ìlà oòrùn,ati àwọn ará Filistia láti ìhà ìwọ̀ oòrùn;wọn óo gbé Israẹli mì.Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró. +Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò pada sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó jẹ wọ́n níyà,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá OLUWA àwọn ọmọ-ogun. +Nítorí náà, OLUWA yóo fi ìyà jẹ Israẹli.Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, yóo gé Israẹli lórí ati nírù. +Àwọn àgbààgbà ati àwọn ọlọ́lá wọn ni orí,àwọn wolii tí ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ èké sì ni ìrù +Àwọn tí ń darí àwọn eniyan wọnyi ń ṣì wọ́n lọ́nà ni,àwọn tí wọn ń tọ́ sọ́nà sì ń já sinu ìparun. +Nítorí náà, OLUWA kò láyọ̀ lórí àwọn ọdọmọkunrin wọn,àánú àwọn aláìníbaba ati àwọn opó wọn kò sì ṣe énítorí pé aṣebi ni gbogbo wọn, wọn kò sì mọ Ọlọrun,ọ̀rọ̀ burúkú ni wọ́n sì ń fi ẹnu wọn sọ.Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró. +Ìwà burúkú wọn ń jó bí iná,tí ń jó ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn.Ó ń jó bíi igbó ńlá, ó sì ń yọ èéfín sókè lálá. +Nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun, ilẹ̀ náà jóná,àwọn eniyan ibẹ̀ dàbí èpò tí a dà sinu ináẹnikẹ́ni kò sì dá ẹnìkejì rẹ̀ sí. +Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri. +Wọ́n ń já nǹkan gbà lọ́tùn-ún, wọ́n ń jẹ ẹ́,sibẹ ebi ń pa wọ́n.Wọ́n ń jẹ àjẹrun lósì,sibẹ wọn kò yó,àwọn eniyan sì ń pa ara wọn jẹ. +Àwọn ará Manase ń bá àwọn ará Efuraimu jà,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Efuraimu náà ń bá àwọn ará Manase jà.Àwọn mejeeji wá dojú ìjà kọ Juda.Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò dáwọ́ ìjà rẹ̀ dúró. +Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà.Ó ti fi kún ayọ̀ wọn;wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè.Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun. +Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn,ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká,ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n.Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani. +Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun,ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun,iná yóo sì jó wọn run. +Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,a fún wa ní ọmọkunrin kan.Òun ni yóo jọba lórí wa.A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn,Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé,Ọmọ-Aládé alaafia. +Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i, alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi.Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀,yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo,láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé.Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí +OLUWA ranṣẹ ìdájọ́ sí Jakọbu,àní, sórí àwọn ọmọ Israẹli. +Gbogbo eniyan ni yóo mọ̀,àwọn ará Efuraimu ati àwọn ará Samaria,àwọn tí wọn ń fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé: +Ìkíni. +Èmi Jakọbu, iranṣẹ Ọlọrun, ati ti Oluwa wa, Jesu Kristi, ni ó ń kọ ìwé yìí sí àwọn ẹ̀yà mejila tí ó fọ́nká gbogbo ayé. Alaafia fun yín! +Bẹ́ẹ̀ ni kí ọlọ́rọ̀ kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, nítorí bí òdòdó koríko ìgbẹ́ ni ọlọ́rọ̀ kò ní sí mọ́. +Nítorí nígbà tí oòrùn bá yọ, tí ó mú, koríko á rọ, òdòdó rẹ̀ á sì rẹ̀, òdòdó tí ó lẹ́wà tẹ́lẹ̀ á wá ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ọlọ́rọ̀ yóo parẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. +Ẹni tí ó bá fi ara da ìdánwò kú oríire, nítorí nígbà tí ó bá yege tán, yóo gba adé ìyè tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀. +Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìdánwò má ṣe sọ pé, “Láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ìdánwò yìí ti wá.” Nítorí kò sí ẹni tí ó lè fi nǹkan burúkú dán Ọlọrun wò. Ọlọrun náà kò sì jẹ́ fi nǹkan burúkú dán ẹnikẹ́ni wò. +Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn olukuluku ni ó ń tàn án, tí ó ń fa ìdánwò. +Nígbà tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá lóyún, á bí ẹ̀ṣẹ̀; nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ bá gbilẹ̀ tán á bí ikú. +Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ má tan ara yín jẹ. +Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀. +Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa, kí á lè jẹ́ àkọ́kọ́ ninu àwọn ẹ̀dá rẹ̀. +Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo fẹ́ kí ẹ mọ nǹkankan: eniyan níláti tètè gbọ́ ọ̀rọ̀, ṣugbọn kí ó lọ́ra láti désì pada, kí ó sì lọ́ra láti bínú. +Ẹ̀yin ará mi, ẹ kà á sí ayọ̀ gidi nígbà tí oríṣìíríṣìí ìdánwò bá dé ba yín. +Nítorí ibinu eniyan kì í yọrí sí ire tí Ọlọrun fẹ́. +Nítorí náà, ẹ mú gbogbo ìwà èérí ati gbogbo ìwàkiwà à-ń-wá-ipò-aṣaaju kúrò, kí á lè wà ní ipò kinni. Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gba ọ̀rọ̀ tí a gbìn sinu yín, tí ó lè gba ọkàn yín là. +Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ ìyìn rere ṣe ìwà hù; ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán. Bí ẹ bá ń gbọ́ lásán, ara yín ni ẹ̀ ń tàn jẹ. +Nítorí bí eniyan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò fi ṣe ìwà hù, olúwarẹ̀ dàbí ẹni tí ó wo ojú ara rẹ̀ ninu dígí. +Ó wo ara rẹ̀ dáradára, ó kúrò níbẹ̀, kíá ó ti gbàgbé bí ojú rẹ̀ ti rí. +Ṣugbọn ẹni tí ó bá wo òfin tí ó pé, tíí ṣe orísun òmìnira, tí ó sì dúró lé e lórí, olúwarẹ̀ kì í ṣe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó gbàgbé rẹ̀, ṣugbọn ó ń fi ọ̀rọ̀ náà ṣe ìwà hù. Olúwarẹ̀ di ẹni ibukun nítorí ó ń fi ọ̀rọ̀ tí ó gbọ́ ṣe ìwà hù. +Bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ olùfọkànsìn, tí kò bá kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni, asán sì ni ẹ̀sìn rẹ̀. +Ẹ̀sìn tí ó pé, tí kò lábàwọ́n níwájú Ọlọrun Baba ni pé kí eniyan máa ran àwọn ọmọ tí kò ní òbí ati àwọn opó lọ́wọ́ ninu ipò ìbànújẹ́ wọn, kí eniyan sì pa ara rẹ̀ mọ́ láìléèérí ninu ayé. +Kí ẹ mọ̀ pé ìdánwò igbagbọ yín ń mú kí ẹ ní ìfaradà. +Ẹ níláti ní ìfaradà títí dé òpin, kí ẹ lè di pípé, kí ẹ sì ní ohun gbogbo lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, láìsí ìkùnà kankan. +Bí ẹnikẹ́ni bá wà ninu yín, tí ọgbọ́n kù díẹ̀ kí ó tó fún, kí olúwarẹ̀ bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun, yóo sì fún un. Nítorí Ọlọrun lawọ́, kì í sìí sìrègún. +Ṣugbọn olúwarẹ̀ níláti bèèrè pẹlu igbagbọ, láì ṣiyèméjì. Nítorí ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dàbí ìgbì omi òkun, tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri tí ó sì ń rú sókè. +Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé òun óo rí nǹkankan gbà lọ́dọ̀ Oluwa: ọkàn rẹ̀ kò papọ̀ sí ọ̀nà kan, ó ń ṣe ségesège, ó ń ṣe iyè meji. +Kí arakunrin tí ó jẹ́ mẹ̀kúnnù kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbé e ga. +Ẹ Má Ṣe Ojuṣaaju. +Ẹ̀yin ará mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní igbagbọ ninu Oluwa wa, Jesu Kristi, Oluwa tí ó lógo, ẹ má máa ṣe ojuṣaaju. +Nítorí ẹni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, ṣugbọn tí ó rú ẹyọ kan ṣoṣo, ó jẹ̀bi gbogbo òfin. +Nítorí ẹnìkan náà tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè,” òun náà ni ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan.” Bí o kò bá ṣe àgbèrè ṣugbọn o paniyan, o ti di arúfin. +Ẹ máa sọ̀rọ̀, kí ẹ sì máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó wà lábẹ́ ìdájọ́ òfin tí ó ń sọ eniyan di òmìnira. +Nítorí kò ní sí àánú ninu ìdájọ́ fún àwọn tí kò ní ojú àánú, bẹ́ẹ̀ sì ni àánú ló borí ìdájọ́. +Ẹ̀yin ará mi, èrè kí ni ó jẹ́, tí ẹnìkan bá sọ pé òun ní igbagbọ, ṣugbọn tí igbagbọ yìí kò hàn ninu iṣẹ́ rẹ̀? Ṣé igbagbọ yìí lè gbà á là? +Bí arakunrin kan tabi arabinrin kan bá wà ní ìhòòhò, tí kò jẹun fún odidi ọjọ́ kan, +tí ẹnìkan ninu yín wá sọ fún un pé, “Máa lọ ní alaafia, Ọlọrun yóo pèsè aṣọ ati oúnjẹ fún ọ,” ṣugbọn tí kò fún olúwarẹ̀ ní ohun tí ó nílò, anfaani wo ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ ṣe? +Bẹ́ẹ̀ gan-an ni igbagbọ tí kò bá ní iṣẹ́: òkú ni. +Ṣugbọn ẹnìkan lè sọ pé, “Ìwọ ní igbagbọ, èmi ní iṣẹ́.” Fi igbagbọ rẹ hàn mí láìsí iṣẹ́, èmi óo fi igbagbọ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ mi. +Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọrun kan ní ń bẹ. Ó dára bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rùbojo sì mú wọn. +Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá wọ àwùjọ yín, tí ó fi òrùka wúrà sọ́wọ́, tí ó wọ aṣọ tí ń dán, tí talaka kan náà bá wọlé tí ó wọ aṣọ tí ó dọ̀tí; +Ìwọ eniyan lásán! O fẹ́ ẹ̀rí pé igbagbọ ti kò ní iṣẹ́ ninu jẹ́ òkú? +Nípa iṣẹ́ kọ́ ni Abrahamu baba wa fi gba ìdáláre, nígbà tí ó fa Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ sí orí pẹpẹ ìrúbọ? +O rí i pé igbagbọ ń farahàn ninu iṣẹ́ rẹ̀, ati pé iṣẹ́ rẹ̀ ni ó ṣe igbagbọ rẹ̀ ní àṣepé. +Èyí ni ó mú kí Ìwé Mímọ́ ṣẹ tí ó sọ pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí olódodo.” A wá pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọrun. +Ṣé ẹ wá rí i pé nípa iṣẹ́ ni eniyan fi ń gba ìdáláre, kì í ṣe nípa igbagbọ nìkan? +Ṣebí bákan náà ni Rahabu aṣẹ́wó gba ìdáláre nípa iṣẹ́, nígbà tí ó ṣe àwọn amí ní àlejò, tí ó jẹ́ kí wọ́n bá ọ̀nà mìíràn pada lọ? +Bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ ni igbagbọ láìsí iṣẹ́. +ẹ óo máa fi ojurere wo ẹni tí ó wọ aṣọ dídán, ẹ óo sọ fún un pé, “Wá jókòó níbi dáradára yìí.” Ṣugbọn ẹ óo wá sọ fún talaka pé, “Dúró níbẹ̀, tabi wá jókòó nílẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ mi níhìn-ín.” +Ǹjẹ́ ẹ kò fi bẹ́ẹ̀ dá ìyapa sílẹ̀ láàrin ara yín, ǹjẹ́ ẹ kò sì máa ṣe ìdájọ́ pẹlu èrò burúkú. +Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. Ọlọrun ti yan àwọn mẹ̀kúnnù ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu igbagbọ ati láti jogún ìjọba tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀. +Ṣugbọn ẹ̀ ń kẹ́gàn mẹ̀kúnnù. Ṣebí àwọn ọlọ́rọ̀ níí máa fìtínà yín, tí wọn máa ń fà yín lọ sí kóòtù! +Ṣebí àwọn ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí orúkọ rere tí a fi ń pè yín! +Ẹ̀ ń ṣe dáradára tí ẹ bá pa òfin ìjọba Ọlọrun mọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé, “Ìwọ fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.” +Ṣugbọn tí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju, ẹ di arúfin, ati ẹni ìbáwí lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́ bí arúfin. +Ahọ́n. +Ẹ̀yin ará mi, kí ọpọlọpọ yín má máa jìjàdù láti jẹ́ olùkọ́ni, kí ẹ mọ̀ pé ìdájọ́ ti àwa olùkọ́ni yóo le. +Láti inú ẹnu kan náà ni ìyìn ati èpè ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, kò yẹ kí èyí rí bẹ́ẹ̀. +Ǹjẹ́ omi dídùn ati omi kíkorò lè ti inú orísun omi kan náà jáde? +Ẹ̀yin ará mi, ṣé igi ọ̀pọ̀tọ́ lè so èso olifi, tabi kí àjàrà kó so ọ̀pọ̀tọ́? Ìsun omi kíkorò kò lè mú omi dídùn jáde. +Ẹnikẹ́ni wà l��àrin yín tí ó gbọ́n, tí ó tún mòye? Kí ó fihàn nípa ìgbé-ayé rere ati ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí ó fi ọgbọ́n hàn. +Ṣugbọn tí ẹ bá ń jowú ara yín kíkankíkan, tí ẹ ní ọkàn ìmọ-tara-ẹni-nìkan, ẹ má máa gbéraga, kí ẹ má sì purọ́ mọ́. +Èyí kì í ṣe ọgbọ́n tí ó wá láti òkè, ọgbọ́n ayé ni, gẹ́gẹ́ bíi ti ẹran-ara, ati ti ẹ̀mí burúkú. +Níbi tí owú ati ìlara bá wà, ìrúkèrúdò ati oríṣìíríṣìí ìwà burúkú a máa wà níbẹ̀. +Ṣugbọn ní àkọ́kọ́, ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ pípé, lẹ́yìn náà a máa mú alaafia wá, a máa ṣe ẹ̀tọ́, a máa ro ọ̀rọ̀ dáradára, a máa ṣàánú; a máa so èso rere, kì í ṣe ẹnu meji, kì í ṣe àgàbàgebè. +Àwọn tí wọn bá ń fúnrúgbìn ire pẹlu alaafia yóo kórè alaafia. +Nítorí gbogbo wa ni à ń ṣe àṣìṣe ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Bí ẹnikẹ́ni bá wà tí kò ṣi ọ̀rọ̀ sọ rí, a jẹ́ pé olúwarẹ̀ pé, ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ níjàánu. +Tí a bá fi ìjánu sí ẹṣin lẹ́nu, kí wọ́n lè ṣe bí a ti fẹ́, a máa darí gbogbo ara wọn bí a bá ti fẹ́. +Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo àwọn ọkọ̀ ojú omi. Bí wọ́n ti tóbi tó, tí ó jẹ́ pé afẹ́fẹ́ líle ní ń gbé wọn kiri, sibẹ ìtukọ̀ kékeré ni ọ̀gá àwọn atukọ̀ fi ń darí wọn sí ibi tí ó bá fẹ́. +Bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n, ẹ̀yà ara kékeré ni, ṣugbọn ìhàlẹ̀ rẹ̀ pọ̀.Ẹ wo bírà tí iná kékeré lè dá ninu igbó ńlá! +Iná ni ahọ́n. Ó kún fún àwọn nǹkan burúkú ayé yìí. Ninu àwọn ẹ̀yà ara wa, ahọ́n ni ó ń kó nǹkan ibi bá gbogbo ara. A máa mú kí gbogbo ara wá gbóná, iná ọ̀run àpáàdì ni ó túbọ̀ ń fún un ní agbára. +Gbogbo ẹ̀dá pátá: ati ẹranko ni, ati ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà, ati àwọn ẹran omi, gbogbo wọn ni eniyan lè so lójú rọ̀. +Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó kápá ahọ́n. Nǹkan burúkú tí ó kanpá ni, ó kún fún oró tí ó lè paniyan kíákíá. +Ahọ́n ni a fi ń yin Oluwa ati Baba. Òun kan náà ni a fi ń ṣépè fún eniyan tí a dá ní àwòrán Ọlọrun. +Bíbá Ayé Rẹ́. +Níbo ni ogun ti ń wá? Níbo ni ìjà sì ti ń wá sáàrin yín? Ṣebí nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yín tí ó ń jagun ninu àwọn ẹ̀yà ara yín ni. +Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Oluwa, yóo wá gbe yín ga. +Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ àbùkù nípa ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa arakunrin rẹ̀ tabi tí ó bá ń dá arakunrin rẹ̀ lẹ́jọ́ ń sọ̀rọ̀ àbùkù sí òfin, ó tún ń dá òfin lẹ́jọ́. Tí ó bá wá ń dá òfin lẹ́jọ́, ó sọ ara rẹ̀ di onídàájọ́ òfin dípò olùṣe ohun tí òfin wí. +Ẹnìkan ṣoṣo ni ó fúnni lófin, tí ó jẹ́ onídàájọ́. Òun ni ẹni tí ó lè gba ẹ̀mí là, tí ó sì lè pa ẹ̀mí run; Ṣugbọn ìwọ, ta ni ọ́ tí o fi ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́? +Ẹ gbọ́ ná, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí pé, “Lónìí, tabi lọ́la, a óo lọ sí ibi báyìí, a óo ṣe ọdún kan níbẹ̀; a óo ṣòwò, a óo sì jèrè.” +Ẹ kò mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín lọ́la. Nítorí ìkùukùu ni yín, tí ó wà fún àkókò díẹ̀, lẹ́yìn náà tí kò ní sí mọ́. +Ohun tí ẹ̀ bá máa wí ni pé “Bí Oluwa bá dá ẹ̀mí sí, a óo ṣe báyìí báyìí.” +Ṣugbọn ẹ̀ ń lérí, ẹ̀ ń fọ́nnu; irú ìlérí báyìí kò dára. +Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ń gbà. +Ẹ̀ ń fẹ́ nǹkankan, ọwọ́ yín kò sì tẹ̀ ẹ́; ẹ bá ń tìtorí rẹ̀ paniyan; ẹ̀ ń jowú nítorí nǹkankan, ọwọ́ yín kò bá ohun tí ẹ̀ ń jowú lé lórí, ẹ bá sọ ọ́ di ọ̀ràn ìjà ati ogun. Ọwọ́ yín kò tẹ ohun tí ẹ fẹ́ nítorí pé ẹ kò bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun. +Bí ẹ bá sì bèèrè, ẹ kò rí ohun tí ẹ bèèrè gbà nítorí èrò burúkú ni ẹ fi bèèrè, kí ẹ lè lo ohun tí ẹ bèèrè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara yín. +Ẹ̀yin àgbèrè, ẹ kò mọ̀ pé ìbá ayé ṣọ̀rẹ́ níláti jẹ́ ìbá Ọlọrun ṣọ̀tá? Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ti yàn láti jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun. +Àbí ẹ rò pé lásán ni Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ẹ̀mí tí ó fi sinu wa ń jowú gidigidi lórí wa?” +Ṣugbọn oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fúnni tóbi ju èyí lọ. Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” +Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun. Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, yóo sì sálọ kúrò lọ́dọ̀ yín. +Ẹ súnmọ́ Ọlọrun, òun óo sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín dá ṣáká, ẹ̀yin oníyèméjì. +Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín bàjẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, ẹ sọkún; ẹ má rẹ́rìn-ín mọ́, ńṣe ni kí ẹ fajúro. Ẹ máa banújẹ́ dípò yíyọ̀ tí ẹ̀ ń yọ̀. +Ìkìlọ̀ fún Àwọn Ọlọ́rọ̀. +Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀. Ẹ máa sọkún, kí ẹ sì máa ké gidi nítorí ìṣẹ́ tí ó ń bọ̀ wá ṣẹ́ yín. +Ẹ̀yin ará, ẹ wo àpẹẹrẹ àwọn wolii, àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ ní orúkọ Oluwa pẹlu sùúrù ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. +Ẹ ranti pé àwọn tí ó bá ní ìfaradà ni à ń pè ní ẹni ibukun. Ẹ ti gbọ́ nípa Jobu, bí ó ti ní ìfaradà, ẹ sì mọ bí Oluwa ti jẹ́ kí ó yọrí sí fún un. Nítorí oníyọ̀ọ́nú ati aláàánú ni Oluwa. +Boríborí gbogbo rẹ̀, ẹ̀yin ará mi, ẹ má máa búra, ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, tabi ilẹ̀, tabi ohun mìíràn. Tí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,” bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ó jẹ́. Bí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,” kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” Kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdájọ́. +Bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá wà ninu ìyọnu, kí olúwarẹ̀ gbadura. Bí inú ẹnikẹ́ni ninu yín bá dùn, kí olúwarẹ̀ máa kọ orin ìyìn. +Bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá ń ṣàìsàn, kí ó pe àwọn àgbà ìjọ jọ, kí wọ́n gbadura fún un, kí wọ́n fi òróró pa á lára ní orúkọ Oluwa. +Adura pẹlu igbagbọ yóo mú kí ara aláìsàn náà yá. Oluwa yóo gbé e dìde, a óo sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá jì í. +Ẹ máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, ẹ máa gbadura fún ara yín kí ẹ lè ní ìwòsàn. Adura àtọkànwá olódodo lágbára, nítorí Ọlọrun a máa fi àṣẹ sí i. +Eniyan ẹlẹ́ran-ara bí àwa ni Elija. Ó fi tọkàntọkàn gbadura pé kí òjò má rọ̀. Òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún odidi ọdún mẹta ati oṣù mẹfa. +Ó tún gbadura, òjò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ láti òkè, ilẹ̀ sì hu ohun ọ̀gbìn jáde. +Ẹ̀yin ará mi, bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá ṣìnà kúrò ninu òtítọ́, tí ẹnìkan bá tọ́ ọ sọ́nà, +Ọrọ̀ yín ti bàjẹ́. Kòkòrò ti jẹ gbogbo aṣọ yín. +ẹ mọ̀ dájú pé ẹni tí ó bá mú ẹlẹ́ṣẹ̀ pada kúrò ninu ìṣìnà rẹ̀ gba ọkàn ẹni náà lọ́wọ́ ikú, ó sì mú kí ìgbàgbé bá ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀. +Wúrà yín ati fadaka yín ti dógùn-ún. Dídógùn-ún wọn ni yóo jẹ́ ẹ̀rí fun yín, nítorí yóo jẹ ara yín bí ìgbà tí iná bá ń jó nǹkan. Inú ayé tí ó fẹ́rẹ̀ dópin ni ẹ̀ ń to ìṣúra jọ sí! +Owó iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ṣiṣẹ́ ní oko yín, tí ẹ kò san fún wọn ń pariwo yín. Igbe àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ba yín kórè oko yín sì ti dé etí Oluwa Ọlọrun Olodumare. +Ẹ̀ ń ṣe fàájì ninu ayé, ẹ̀ ń jẹ, ẹ̀ ń mu. Ẹ wá sanra bíi mààlúù, bẹ́ẹ̀ sì ni ọjọ́ tí wọn yóo dumbu mààlúù ló kù sí dẹ̀dẹ̀ yìí. +Ẹ gbé ẹ̀bi fún aláre, ẹ sì pa á, kò lè rú pútú. +Ẹ̀yin ará, ẹ mú sùúrù títí Oluwa yóo fi dé. Ẹ wo àgbẹ̀ tí ó ń retí èso tí ó dára ninu oko, ó níláti mú sùúrù fún òjò àkọ́rọ̀ ati òjò àrọ̀kẹ́yìn. +Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin gan-an mú sùúrù. Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, nítorí Oluwa fẹ́rẹ̀ dé. +Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe bá ara yín wí, kí á má baà da yín lẹ́jọ́. Onídàájọ́ ti dúró lẹ́nu ọ̀nà. +Àwọn Ẹ̀yà Juda ati ti Simeoni Ṣẹgun Adonibeseki. +Lẹ́yìn ikú Joṣua, àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ẹ̀yà wo ni kí ó kọ́kọ́ gbógun ti àwọn ará Kenaani?” +Àwọn ọmọ Juda tún lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ìlú Heburoni, (Kiriati Araba ni orúkọ tí wọn ń pe Heburoni tẹ́lẹ̀); wọ́n ṣẹgun Ṣeṣai, Ahimani ati Talimai. +Nígbà tí wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ gbógun ti ìlú Debiri. (Kiriati Seferi ni orúkọ tí wọ́n ń pe Debiri tẹ́lẹ̀.) +Kalebu ní ẹnikẹ́ni tí ó bá gbógun ti ìlú Kiriati Seferi tí ó sì ṣẹgun rẹ̀, ni òun óo fi Akisa, ọmọbinrin òun fún kí ó fi ṣe aya. +Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, ṣẹgun ìlú náà, Kalebu bá fi Akisa, ọmọbinrin rẹ̀ fún un kí ó fi ṣe aya. +Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tọrọ pápá ìdaran lọ́wọ́ baba rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, Akisa lọ bá baba rẹ̀, bí ó ti ń sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni baba rẹ̀ bi í pé, “Kí lo fẹ́?” +Ó bá dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Ẹ̀bùn kan ni mo fẹ́ tọrọ. Ṣé o mọ̀ pé ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni o fún mi; nítorí náà, fún mi ní orísun omi pẹlu rẹ̀.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí ó wà ní òkè ati ní ìsàlẹ̀. +Àwọn ọmọ ọmọ Keni, àna Mose, bá àwọn ọmọ Juda lọ láti Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ, sí inú aṣálẹ̀ Juda tí ó wà ní apá ìhà gúsù lẹ́bàá Aradi; wọ́n sì jọ ń gbé pọ̀ níbẹ̀. +Àwọn ọmọ Juda bá àwọn ọmọ Simeoni, arakunrin wọn, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Sefati. Wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n run wọ́n patapata, wọ́n sì sọ ìlú náà ní Horima. +Àwọn ọmọ Juda ṣẹgun ìlú Gasa ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè rẹ̀. Wọ́n ṣẹgun ìlú Aṣikeloni ati Ekironi ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè wọn. +OLUWA wà pẹlu àwọn ọmọ Juda, ọwọ́ wọn tẹ àwọn ìlú olókè, ṣugbọn apá wọn kò ká àwọn tí ó ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé irin ni wọ́n fi ṣe kẹ̀kẹ́ ogun wọn. +OLUWA dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yà Juda ni kí ó kọ́ dojú kọ wọ́n, nítorí pé, mo ti fi ilẹ̀ náà lé wọn lọ́wọ́.” +Wọ́n fún Kalebu ní Heburoni gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí, Kalebu sì lé àwọn ọmọ Anaki mẹtẹẹta kúrò níbẹ̀. +Ṣugbọn àwọn ọmọ Bẹnjamini kò lé àwọn ará Jebusi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu jáde; láti ìgbà náà ni àwọn ará Jebusi ti ń bá àwọn ọmọ Bẹnjamini gbé ní Jerusalẹmu títí di òní olónìí. +Àwọn ọmọ Josẹfu náà gbógun ti ìlú Bẹtẹli, OLUWA sì wà pẹlu wọn. +Wọ́n rán àwọn amí láti lọ wo Bẹtẹli. (Lusi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀.) +Àwọn amí náà rí ọkunrin kan tí ń jáde bọ̀ láti inú ìlú náà, wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, fi ọ̀nà tí a óo gbà wọ ìlú yìí hàn wá, a óo sì ṣe ọ́ lóore.” +Ọkunrin náà bá fi ọ̀nà tí wọn ń gbà wọ ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n bá fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà, ṣugbọn wọ́n jẹ́ kí ọkunrin náà ati gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde lọ. +Ọkunrin náà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hiti, ó tẹ ìlú kan dó, ó sì sọ ọ́ ní Lusi. Orúkọ náà ni wọ́n ń pe ìlú náà títí di òní olónìí. +Àwọn ọmọ Manase kò lé àwọn ará ìlú Beti Ṣeani ati àwọn ará Taanaki jáde, ati àwọn ará Dori, àwọn ará Ibileamu, àwọn ará Megido ati àwọn tí wọn ń gbé gbogbo àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká àwọn ìlú náà; ṣugbọn àwọn ará Kenaani ṣì ń gbé ilẹ̀ náà. +Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára sí i, wọ́n ń fi tipátipá kó àwọn ará Kenaani ṣiṣẹ́, ṣugbọn wọn kò lé wọn kúrò láàrin wọn patapata. +Àwọn ọmọ Efuraimu kò lé àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Geseri jáde, wọ́n jẹ́ kí wọ́n máa gbé ààrin wọn. +Àwọn ọmọ Juda bá tọ ẹ̀yà Simeoni, arakunrin wọn lọ, wọ́n ní, “Ẹ bá wa lọ síbi ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wa, kí á lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani. Nígbà tí ó bá yá, àwa náà yóo ba yín lọ síbi ilẹ̀ tí wọ́n pín fun yín.” Àwọn ẹ̀yà Simeoni bá tẹ̀lé wọn. +Àwọn ọmọ Sebuluni kò lé àwọn tí wọ́n ń gbé ìlú Kitironi jáde, ati àwọn tí ó ń gbé Nahalali, ṣugbọn àwọn ará Kenaani ń bá wọn gbé, àwọn ọmọ Sebuluni sì ń fi tipátipá kó wọn ṣiṣẹ́. +Àwọn ọmọ Aṣeri náà kò lé àwọn wọnyi jáde: àwọn ará Ako ati àwọn ará Sidoni, àwọn ará Ahilabu ati àwọn ará Akisibu, àwọn ará Heliba ati àwọn ará Afeki, ati àwọn ará Rehobu. +Ṣugbọn àwọn ọmọ Aṣeri ń gbé ààrin àwọn ará Kenaani tí wọ́n bá ní ilẹ̀ náà, nítorí pé wọn kò lé wọn jáde. +Àwọn ará Nafutali kò lé àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ati àwọn ará Betanati jáde, ṣugbọn wọ́n ń gbé ààrin àwọn tí wọ́n bá ni ilẹ̀ Kenaani. Ṣugbọn wọ́n ń fi tipátipá kó àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ati ti Betanati ṣiṣẹ́. +Àwọn ará Amori ń lé àwọn ọmọ Dani sẹ́yìn sí àwọn agbègbè olókè, nítorí pé wọn kò fẹ́ gba àwọn ọmọ Dani láàyè rárá láti sọ̀kalẹ̀ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀. +Àwọn ará Amori kọ̀, wọn kò jáde ní òkè Heresi, Aijaloni ati Ṣaalibimu, ṣugbọn àwọn ọmọ Josẹfu kò fi wọ́n lọ́rùn sílẹ̀ títí tí àwọn ọmọ Josẹfu fi bẹ̀rẹ̀ sí fi tipátipá kó wọn ṣiṣẹ́. +Ààlà àwọn ará Amori bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ̀ òkè Akirabimu, láti Sela lọ sókè. +Àwọn ọmọ Juda gbéra, wọ́n lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. OLUWA fi wọ́n lé àwọn ọmọ Juda lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹgun ẹgbaarun (10,000) ninu wọn ní Beseki. +Wọ́n bá Adonibeseki ní Beseki, wọ́n gbógun tì í, wọ́n sì ṣẹgun àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. +Adonibeseki sá, ṣugbọn wọ́n lé e mú. Wọ́n gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji. +Adonibeseki bá dáhùn pé, “Aadọrin ọba tí mo ti gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ wọn, ni wọ́n máa ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tabili mi. Ẹ̀san ohun tí mo ṣe sí wọn ni Ọlọrun ń san fún mi yìí.” Wọ́n bá mú un wá sí Jerusalẹmu, ibẹ̀ ni ó sì kú sí. +Àwọn ọmọ Juda gbógun ti ìlú Jerusalẹmu; wọ́n gbà á, wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbébẹ̀, wọ́n sì sun ún níná. +Lẹ́yìn náà, wọ́n gbógun ti àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí wọ́n ń gbé orí òkè, ati ìhà gúsù tí à ń pè ní Nẹgẹbu, ati àwọn tí wọn ń gbé ẹsẹ̀ òkè náà pẹlu. +Tola. +Lẹ́yìn tí Abimeleki kú, Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, láti inú ẹ̀yà Isakari ni ó dìde tí ó sì gba Israẹli kalẹ̀. Ìlú Ṣamiri tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu ni ìlú rẹ̀. +Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA, wọ́n ní, “A ti sẹ̀ sí ọ, nítorí pé a ti kọ ìwọ Ọlọrun wa sílẹ̀ a sì ń bọ àwọn oriṣa Baali.” +OLUWA bá dá àwọn ọmọ Israẹli lóhùn, ó ní, “Ṣebí èmi ni mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ati àwọn ara Amori, ati àwọn ará Amoni ati àwọn ará Filistia. +Nígbà tí àwọn ará Sidoni, àwọn ará Amaleki, ati àwọn ará Maoni ń pọn yín lójú; ẹ kígbe pè mí, mo sì gbà yín lọ́wọ́ wọn. +Sibẹsibẹ ẹ tún kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń bọ oriṣa. Nítorí náà n kò ní gbà yín là mọ́. +Ẹ lọ bá àwọn oriṣa tí ẹ ti yàn, kí ẹ ké pè wọ́n, kí àwọn náà gbà yín ní ìgbà ìpọ́njú.” +Àwọn ọmọ Israẹli bá dá OLUWA lóhùn pé, “A ti dẹ́ṣẹ̀, fi wá ṣe ohun tí ó bá wù ọ́. Jọ̀wọ́, ṣá ti gbà wá kalẹ̀ lónìí ná.” +Wọ́n bá kó gbogbo àwọn àjèjì oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA. Inú bí OLUWA, nítorí ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli. +Àwọn ọmọ ogun Amoni múra ogun, wọ́n pàgọ́ sí Gileadi, àwọn ọmọ ogun Israẹli náà bá kó ara wọn jọ, wọ́n pàgọ́ tiwọn sí Misipa. +Àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà Gileadi sì bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Ta ni yóo kọ́kọ́ ko àwọn ọmọ ogun Amoni lójú?” Wọ́n ní, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ kò wọ́n lójú ni yóo jẹ́ olórí fún gbogbo àwa ará Gileadi.” +Ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹtalelogun, nígbà tí ó ṣaláìsí wọ́n sin ín sí Ṣamiri. +Jairi ará Gileadi ni ó di adájọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mejilelogun. +Ó bí ọgbọ̀n ọmọkunrin, tí wọ́n ń gun ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọgbọ̀n ìlú ni wọ́n sì tẹ̀dó, tí wọn ń pe orúkọ wọn ní Hafoti Jairi títí di òní olónìí. Wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi. +Nígbà tí Jairi ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí ilẹ̀ Kamoni. +Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, ati Aṣitarotu, oriṣa àwọn ará Siria ati àwọn ará Sidoni, ti àwọn ará Moabu ati àwọn ará Amoni, ati ti àwọn ará Filistia. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọn kò sìn ín mọ́. +Inú tún bí OLUWA sí Israẹli ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia ati àwọn ará Amoni lọ́wọ́. +Odidi ọdún mejidinlogun ni wọ́n fi ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní òdìkejì odò Jọdani, ní Gileadi lára. Gileadi yìí wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni. +Àwọn ará Amoni sì tún kọjá sí òdìkejì odò Jọdani, wọ́n bá àwọn ẹ̀yà Juda, ẹ̀yà Bẹnjamini ati ẹ̀yà Manase jà, gbogbo Israẹli patapata ni wọ́n ń pọ́n lójú. +Ọmọbinrin Jẹfuta. +Jẹfuta ará Gileadi jẹ́ akikanju jagunjagun, ṣugbọn ọmọ aṣẹ́wó ni; Gileadi ni baba rẹ̀. +Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “OLUWA ni ẹlẹ́rìí láàrin àwa pẹlu rẹ pé, ohun tí o bá wí ni a óo ṣe.” +Jẹfuta bá àwọn àgbààgbà Gileadi pada lọ, àwọn ará Gileadi sì fi jẹ balogun wọn. Ó lọ siwaju OLUWA ní Misipa, ó sì sọ àdéhùn tí ó bá àwọn àgbààgbà Gileadi ṣe. +Lẹ́yìn náà, Jẹfuta ranṣẹ sí ọba àwọn ará Amoni pé, “Kí ni mo ṣe tí o fi gbógun ti ilẹ̀ mi.” +Ọba Amoni bá rán àwọn oníṣẹ́ pada sí Jẹfuta pé, “Nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ gba ilẹ̀ mi, láti Anoni títí dé odò Jaboku, títí lọ kan odò Jọdani. Nítorí náà, ẹ yára dá ilẹ̀ náà pada ní alaafia.” +Jẹfuta tún ranṣẹ pada sí ọba Amoni pé, +“Gbọ́ ohun tí èmi Jẹfuta wí, Israẹli kò gba ilẹ̀ kankan lọ́wọ́ àwọn ará Moabu tabi lọ́wọ́ àwọn ará Amoni. +Ṣugbọn nígbà tí wọn ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ààrin aṣálẹ̀ ni wọ́n gbà títí wọ́n fi dé Òkun Pupa, tí wọ́n sì fi dé Kadeṣi. +Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rán oníṣẹ́ sí ọba Edomu, wọ́n ní, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ yín kọjá.’ Ṣugbọn ọba Edomu kò gbà wọ́n láàyè rárá, bákan náà, wọ́n ranṣẹ sí ọba Moabu, òun náà kò fún wọn láàyè, àwọn ọmọ Israẹli bá jókòó sí Kadeṣi. +Wọ́n bá gba aṣálẹ̀, wọ́n sì yípo lọ sí òdìkejì ilẹ̀ àwọn ará Edomu ati ti àwọn ará Moabu, títí tí wọ́n fi dé apá ìlà oòrùn ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Wọ́n pàgọ́ wọn sí òdìkejì ilẹ̀ Anoni. Ṣugbọn wọn kò wọ inú ilẹ̀ àwọn ará Moabu, nítorí pé, ààlà ilẹ̀ Moabu ni Anoni wà. +Israẹli bá tún rán oníṣẹ́ sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ó wà ní ìlú Heṣiboni, wọ́n ní, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ rẹ kọjá lọ sí agbègbè ilẹ̀ tiwa.’ +Ṣugbọn iyawo Gileadi gan-an bí àwọn ọmọkunrin mìíràn. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin wọnyi dàgbà, wọ́n lé Jẹfuta jáde, wọ́n sọ fún un pé, “O kò lè bá wa pín ninu ogún baba wa, nítorí ọmọ obinrin mìíràn ni ọ́.” +Ṣugbọn Sihoni kò ní igbẹkẹle ninu àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn kọjá láàrin ilẹ̀ rẹ̀. Ó bá kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ jọ, wọ́n pàgọ́ sí Jahasi, wọ́n sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli. +OLUWA Ọlọrun Israẹli bà fi Sihoni ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́, Israẹli ṣẹgun wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọ́n ń gbé agbègbè náà. +Wọ́n gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amori láti Anoni títí dé odò Jaboku ati láti aṣálẹ̀ títí dé odò Jọdani. +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli ni ó gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ará Amori fún àwọn ọmọ Israẹli. Ṣé ìwọ wá fẹ́ gbà á ni? +Ṣé ohun tí Kemoṣi, oriṣa rẹ fún ọ, kò tó ọ ni? Gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun wa ti gbà fún wa ni a óo fọwọ́ mú. +Ṣé ìwọ sàn ju Balaki, ọmọ Sipori, ọba Moabu lọ ni? Ǹjẹ́ Balaki bá àwọn ọmọ Israẹli ṣe ìjàngbọ̀n kan tabi kí ó bá wọn jagun rí? +Fún nǹkan bí ọọdunrun (300) ọdún tí Israẹli fi ń gbé Heṣiboni ati Aroeri, ati àwọn ìletò tí ó wà ní agbègbè wọn, ati àwọn ìlú ńláńlá tí ó wà ní etí odò Anoni, kí ló dé tí o kò fi gba ilẹ̀ rẹ láàrin àkókò náà? +Nítorí náà, n kò ṣẹ̀ ọ́ rárá, ìwọ ni o ṣẹ̀ mí, nítorí pé o gbógun tì mí. Kí OLUWA onídàájọ́ dájọ́ lónìí láàrin àwọn ọmọ Israẹli ati Amoni.” +Ṣugbọn ọba àwọn ará Amoni kò tilẹ̀ fetí sí iṣẹ́ tí Jẹfuta rán sí i rárá. +Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé Jẹfuta, ó bá kọjá láàrin Gileadi ati Manase, ó lọ sí Misipa ní ilẹ̀ Gileadi, láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Amoni. +Jẹfuta bá sá jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀, ó ń gbé ilẹ̀ Tobu. Àwọn aláìníláárí ati àwọn oníjàgídíjàgan kan bá kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá ń bá a digun jalè káàkiri. +Jẹfuta bá jẹ́jẹ̀ẹ́ kan sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, bí o bá ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá ṣẹgun àwọn ara Amoni, +nígbà tí mo bá ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ṣẹgun wọn tán, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ jáde láti wá pàdé mi láti inú ilé mi, yóo jẹ́ ti ìwọ OLUWA, n óo sì fi rú ẹbọ sísun sí ọ.” +Jẹfuta bá rékọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Amoni láti bá wọn jagun, OLUWA sì fún un ní ìṣẹ́gun. +Ó bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n láti Aroeri títí dé agbègbè Miniti tí ó fi wọ Abeli Keramimu. Àwọn ìlú tí ó run jẹ́ ogún. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣẹgun àwọn ará Amoni. +Jẹfuta bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nì Misipa, bí ó ti ń wọ̀lú bọ̀, ọmọ rẹ̀ obinrin wá pàdé rẹ̀ pẹlu ìlù ati ijó, ọmọbinrin yìí sì ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó bí. +Bí ó ti rí i, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó ní, “Ha! Ọmọ mi, ìwọ ni o kó mi sinu ìbànújẹ́ yìí? Ó ṣe wá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìrẹ ni yóo kó ìbànújẹ́ bá mi? Nítorí pé mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú OLUWA n kò sì gbọdọ̀ má mú un ṣẹ.” +Ọmọbinrin náà dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Baba mi, bí o bá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan níwájú OLUWA, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbẹ̀san lára àwọn ará Amoni, tí í ṣe ọ̀tá rẹ.” +Ó bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Kinní kan ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi, fi mí sílẹ̀ fún oṣù meji, kí èmi ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi lọ sí orí òkè kí á máa káàkiri, kí á sì máa sọkún, nítorí pé mo níláti kú láì mọ ọkunrin.” +Baba rẹ̀ bá ní kí ó máa lọ fún oṣù meji. Òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá lọ sí orí òkè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, nítorí pé ó níláti kú, láì mọ ọkunrin. +Lẹ́yìn oṣù meji, ó pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀, baba rẹ̀ sì ṣe bí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun yóo ṣe, ọmọbinrin náà kò mọ ọkunrin rí rárá.Ó sì di àṣà ní ilẹ̀ Israẹli, +Nígbà tí ó yá, àwọn ará Amoni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli. +pé kí àwọn ọmọbinrin Israẹli máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ ọmọbinrin Jẹfuta, ará Gileadi fún ọjọ́ mẹrin lọdọ���dun. +Nígbà tí ogun yìí bẹ̀rẹ̀, àwọn àgbààgbà Gileadi lọ mú Jẹfuta wá láti ilẹ̀ Tobu. +Wọ́n bẹ Jẹfuta, wọ́n ní, “A fẹ́ lọ gbógun ti àwọn ará Amoni, ìwọ ni a sì fẹ́ kí o jẹ́ balogun wa.” +Ṣugbọn Jẹfuta dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí ẹ̀yin ni ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ fi lé mi jáde kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi wá sọ́dọ̀ mi nígbà tí ìyọnu dé ba yín?” +Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “Ìyọnu tí ó dé bá wa náà ni ó mú kí á wá sọ́dọ̀ rẹ; kí o lè bá wa lọ, láti lọ gbógun ti àwọn ará Amoni. Ìwọ ni a fẹ́ kí o jẹ balogun gbogbo àwa ará Gileadi patapata.” +Ó bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ bá mú mi pada wálé, láti bá àwọn ará Amoni jagun, bí OLUWA bá sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ tí mo ṣẹgun wọn, ṣé ẹ gbà pé kí n máa ṣe olórí yín?” +Jẹfuta ati Àwọn Ará Efuraimu. +Àwọn ọmọ Efuraimu múra ogun, wọ́n ré odò Jọdani kọjá lọ sí Safoni. Wọ́n bi Jẹfuta léèrè pé, “Kí ló dé tí o fi rékọjá lọ sí òdìkejì láti bá àwọn ará Amoni jagun tí o kò sì pè wá pé kí á bá ọ lọ? Jíjó ni a óo jó ilé mọ́ ọ lórí.” +Nígbà tí Ibisani ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Bẹtilẹhẹmu. +Lẹ́yìn Ibisani, Eloni, láti inú ẹ̀yà Sebuluni, jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹ́wàá. +Nígbà tí Eloni ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Aijaloni ní ilẹ̀ Sebuluni. +Lẹ́yìn rẹ̀, Abidoni, ọmọ Hileli, ará Piratoni, jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli. +Ó ní ogoji ọmọkunrin ati ọgbọ̀n ọmọ ọmọ lọkunrin, tí wọn ń gun aadọrin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹjọ. +Lẹ́yìn náà, Abidoni ọmọ Hileli ará Piratoni ṣaláìsí, wọ́n sì sin ín sí Piratoni, ní ilẹ̀ Efuraimu, ní agbègbè olókè àwọn ará Amaleki. +Jẹfuta bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Nígbà kan tí ogun bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Amoni ati èmi pẹlu àwọn eniyan mi, tí mo ranṣẹ pè yín, ẹ kò gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn. +Mo sì ti mọ̀ pé ẹ kò tún ní gbà wá sílẹ̀, ni mo ṣe fi ẹ̀mí mi wéwu, tí mo sì kọjá sí òdìkejì lọ́dọ̀ àwọn ará Amoni; OLUWA sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn. Kí ló wá dé tí ẹ fi dìde sí mi lónìí láti bá mi jà?” +Jẹfuta bá kó gbogbo àwọn ọkunrin Gileadi jọ, wọ́n gbógun ti àwọn ará Efuraimu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n, nítorí pé àwọn ará Efuraimu pe àwọn ará Gileadi ní ìsáǹsá Efuraimu, tí ó wà láàrin ẹ̀yà Efuraimu ati ẹ̀yà Manase. +Àwọn ará Gileadi gba àwọn ipadò odò Jọdani lọ́wọ́ àwọn ará Efuraimu. Nígbà tí ìsáǹsá ará Efuraimu kan bá ń sá bọ̀, tí ó bá sọ fún àwọn ará Gileadi pé, “Ẹ jẹ́ kí n rékọjá.” Àwọn ará Gileadi á bi í pé, “Ǹjẹ́ ará Efuraimu ni ọ́?” Bí ó bá sọ pé, “Rárá,” +wọn á ní kí ó pe, “Ṣiboleti.” Tí kò bá le pè é dáradára, tí ó bá wí pé, “Siboleti,” wọn á kì í mọ́lẹ̀, wọn á sì pa á létí odò Jọdani náà. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe pa ọ̀kẹ́ meji ati ẹgbaa (42,000) eniyan, ninu àwọn ará Efuraimu ní ọjọ́ náà. +Jẹfuta ṣe aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹfa. Nígbà tí ó ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Gileadi, ìlú rẹ̀. +Lẹ́yìn Jẹfuta, Ibisani ará Bẹtilẹhẹmu ni aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli. +Ó bí ọmọkunrin mejilelọgbọn, ó sì ní ọgbọ̀n ọmọbinrin. Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin fọ́kọ láàrin àwọn tí wọn kì í ṣe ìbátan rẹ̀, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n ọmọbinrin láti inú ẹ̀yà mìíràn wá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin. Ó jẹ́ aṣiwaju ní Israẹli fún ọdún meje. +Ìbí Samsoni. +Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Wọ́n sin àwọn ará Filistia fún ogoji ọdún. +Obinrin náà bá sáré lọ sọ fún ọkọ rẹ̀, ó ní, “Ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ mi níjọ́sí tún ti fara hàn mí.” +Manoa bá gbéra, ó bá tẹ̀lé iyawo rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ọkunrin náà, ó bi í pé, “Ṣé ìwọ ni o bá obinrin yìí sọ̀rọ̀?”Ọkunrin náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” +Manoa tún bèèrè pé, “Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ, báwo ni ìgbé ayé ọmọ náà yóo rí? Irú kí ni yóo sì máa ṣe?” +Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí mo sọ fún obinrin yìí ni kí o kíyèsí. +Kò gbọdọ̀ fẹnu kan ohunkohun tí ó bá jáde láti inú èso àjàrà, kò gbọdọ̀ mu waini tabi ọtí líle tabi kí ó jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un ni kí ó ṣe.” +Manoa dá angẹli OLUWA náà lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́, dúró díẹ̀ kí á se ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọ.” +Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Bí o bá dá mi dúró, n kò ní jẹ ninu oúnjẹ rẹ, ṣugbọn tí o bá fẹ́ tọ́jú ohun tí o fẹ́ fi rú ẹbọ sísun, OLUWA ni kí o rú u sí.” Manoa kò mọ̀ pé angẹli OLUWA ni. +Manoa bá bèèrè lọ́wọ́ angẹli OLUWA náà, ó ní, “Kí ni orúkọ rẹ kí á lè dá ọ lọ́lá nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ.” +Angẹli OLUWA náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń bèèrè orúkọ mi nígbà tí ó jẹ́ pé ìyanu ni?” +Manoa bá mú ọmọ ewúrẹ́ náà, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ, ó fi wọ́n rúbọ lórí òkúta kan sí OLUWA tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu. +Ọkunrin kan wà, ará Sora, láti inú ẹ̀yà Dani, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Manoa; àgàn ni iyawo rẹ̀, kò bímọ. +Nígbà tí ọwọ́ iná ẹbọ náà bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè láti orí pẹpẹ, angẹli OLUWA náà bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ ninu ọwọ́ iná orí pẹpẹ náà, bí Manoa ati iyawo rẹ̀ ti ń wò ó. Wọ́n bá dojú wọn bolẹ̀. +Angẹli OLUWA náà kò tún fara han Manoa ati iyawo rẹ̀ mọ́. Manoa wá mọ̀ nígbà náà pé, angẹli OLUWA ni. +Manoa bá sọ fún iyawo rẹ̀ pé, “Dájúdájú, a óo kú, nítorí pé a ti rí Ọlọrun.” +Ṣugbọn iyawo rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Bí ó bá ṣe pé OLUWA fẹ́ pa wá ni, kò ní gba ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ tí a rú sí i lọ́wọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi nǹkan wọnyi hàn wá, tabi kí ó sọ wọ́n fún wa.” +Nígbà tí ó yá, obinrin náà bí ọmọkunrin kan, ó sì sọ ọ́ ní Samsoni. Ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, OLUWA sì bukun un. +Ẹ̀mí OLUWA sì bẹ̀rẹ̀ sí lò ó ní Mahanedani, tí ó wà láàrin Sora ati Eṣitaolu. +Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, angẹli OLUWA fi ara han iyawo Manoa yìí, ó wí fún un pé, “Lóòótọ́, àgàn ni ọ́, ṣugbọn o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan. +Nítorí náà, ṣọ́ra, o kò gbọdọ̀ mu ọtí waini tabi ọtí líle, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́. +Nítorí pé, o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan. Abẹ kò gbọdọ̀ kan orí rẹ̀, nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀; òun ni yóo sì gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.” +Obinrin náà bá lọ sọ fún ọkọ rẹ̀, ó ní, “Eniyan Ọlọrun kan tọ̀ mí wá, ìrísí rẹ̀ jọ ìrísí angẹli Ọlọrun. Ó bani lẹ́rù gidigidi. N kò bèèrè ibi tí ó ti wá, kò sì sọ orúkọ ara rẹ̀ fún mi. +Ṣugbọn ó wí fún mi pé, n óo lóyún, n óo sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní n kò gbọdọ̀ mu ọtí waini, tabi ọtí líle. N kò sì gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́; nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni ọmọ náà yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí yóo fi jáde láyé.” +Manoa bá gbadura sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, jọ̀wọ́ jẹ́ kí iranṣẹ rẹ tí o rán sí wa tún pada wá, kí ó wá kọ́ wa bí a óo ṣe máa tọ́jú ọmọkunrin tí a óo bí.” +Ọlọrun gbọ́ adura Manoa, angẹli Ọlọrun náà tún pada tọ obinrin yìí wá níbi tí ó jókòó sí ninu oko; ṣugbọn Manoa, ọkọ rẹ̀, kò sí lọ́dọ̀ rẹ̀. +Samsoni ati Ọmọbinrin Kan, Ará Timna. +Samsoni lọ sí Timna, ó rí ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin ará Filistia níbẹ̀. +Baba rẹ̀ bá lọ sí ọ̀dọ̀ obinrin náà. Samsoni se àsè ńlá kan níbẹ̀, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọdọmọkunrin máa ń ṣe nígbà náà. +Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i, wọ́n mú ọgbọ̀n ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wá láti wà pẹlu rẹ̀. +Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fun yín, bí ẹ bá lè túmọ̀ àlọ́ náà láàrin ọjọ́ meje tí a ó fi se àsè igbeyawo yìí, n óo fun yín ní ọgbọ̀n ẹ̀wù funfun ati ọgbọ̀n aṣọ àríyá. +Ṣugbọn bí ẹ kò bá lè túmọ̀ àlọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóo fún mi ní ẹ̀wù funfun kọ̀ọ̀kan ati aṣọ àríyá kọ̀ọ̀kan.”Wọ́n bá dáhùn pé, “Pa àlọ́ rẹ kí á gbọ́.” +Ó bá pa àlọ́ náà fún wọn, ó ní,“Láti inú ọ̀jẹun ni nǹkan jíjẹ tií wá,láti inú alágbára sì ni nǹkan dídùn tií wá.”Wọn kò sì lè túmọ̀ àlọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. +Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹrin, wọ́n wá bẹ iyawo Samsoni pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún wa, láì ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sun ìwọ ati ilé baba rẹ níná. Àbí pípè tí o pè wá wá sí ibí yìí, o fẹ́ sọ wá di aláìní ni?” +Iyawo Samsoni bá bẹ̀rẹ̀ sì sọkún níwájú rẹ̀, ó ní, “O kò fẹ́ràn mi rárá, irọ́ ni ò ń pa fún mi. O kórìíra mi; nítorí pé o pa àlọ́ fún àwọn ará ìlú mi, o kò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.”Samsoni bá dá a lóhùn pé, “Ohun tí n kò sọ fún baba tabi ìyá mi, n óo ti ṣe wá sọ f��n ọ?” +Ni iyawo rẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún títí gbogbo ọjọ́ mejeeje tí wọ́n fi se àsè náà. Ṣugbọn nígbà tí ó di ọjọ́ keje, Samsoni sọ fún un, nítorí pé ó fún un lọ́rùn gidigidi. Obinrin náà bá lọ sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ará ìlú rẹ̀. +Nígbà tí ó di ọjọ́ keje, kí ó tó di pé oòrùn wọ̀, àwọn ará ìlú rẹ̀ náà wá sọ ìtumọ̀ àlọ́ Samsoni wí pé,“Kí ló dùn ju oyin lọ;kí ló lágbára ju kinniun lọ?”Ó ní,“Bí kò bá jẹ́ pé mààlúù mi ni ẹ fi tulẹ̀,ẹ kì bá tí lè túmọ̀ àlọ́ mi.” +Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé e tagbára tagbára, ó lọ sí Aṣikeloni, ó sì pa ọgbọ̀n ninu àwọn ọkunrin ìlú náà, ó kó ìkógun wọn, ó sì fún àwọn tí wọ́n túmọ̀ àlọ́ rẹ̀ ní aṣọ àríyá wọn; ó bá pada lọ sí ilé baba rẹ̀ pẹlu ibinu. +Ó pada wálé wá sọ fún baba ati ìyá rẹ̀, ó ní, “Mo rí ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin ará Filistia ní Timna, ó wù mí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fẹ́ ẹ fún mi.” +Wọ́n bá fi iyawo rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní àkókò igbeyawo. +Baba ati ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Ṣé kò sí obinrin mọ́ ninu gbogbo àwọn ìbátan rẹ tabi láàrin gbogbo àwọn eniyan wa ni o fi níláti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ará Filistia aláìkọlà ni?”Samsoni bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Ẹ ṣá fẹ́ ẹ fún mi nítorí ó wù mí pupọ.” +Ṣugbọn baba ati ìyá rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ náà ní ọwọ́ OLUWA ninu, nítorí pé OLUWA ti ń wá ọ̀nà láti mú àwọn ará Filistia nítorí pé, àwọn ni wọ́n ń mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àkókò yìí. +Samsoni bá baba ati ìyá rẹ̀ lọ sí Timna ní ọjọ́ kan. Bí ó ti dé ibi ọgbà àjàrà àwọn ará Timna kan báyìí, ni ọ̀dọ́ kinniun kan bá bú mọ́ ọn. +Ẹ̀mí OLUWA bà lé e, ó sì fún un ní agbára ńlá, ó bá fa kinniun náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí ìgbà tí eniyan ya ọmọ ewúrẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò mú ohunkohun lọ́wọ́. Ṣugbọn kò sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún baba tabi ìyá rẹ̀. +Lẹ́yìn náà, ó lọ bá ọmọbinrin náà sọ̀rọ̀. Ọmọbinrin náà wù ú gidigidi. +Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, ni ó pada lọ láti lọ mú iyawo rẹ̀. Bí ó ti ń lọ, ó yà wo òkú kinniun tí ó pa, ó bá ọ̀wọ́ oyin ati afárá oyin lára rẹ̀. +Ó bá yọ́ ninu afárá oyin náà sí ọwọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí lá a bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó bá baba ati ìyá rẹ̀, ó fún wọn lá ninu rẹ̀; ṣugbọn kò sọ fún wọn pé ara òkú kinniun ni òun ti rẹ́ afárá oyin náà. +Samsoni Ṣẹgun Àwọn Ará Filistia. +Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè ọkà, Samsoni mú ọmọ ewúrẹ́ kan, ó lọ bẹ iyawo rẹ̀ wò. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó ní, “Mo fẹ́ wọlé lọ bá iyawo mi ninu yàrá.”Ṣugbọn baba iyawo rẹ̀ kò jẹ́ kí ó wọlé lọ bá a. +Àwọn ọkunrin Juda bá bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi gbógun tì wá?”Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni ni a wá mú; ohun tí ó ṣe sí wa ni àwa náà fẹ́ ṣe sí i.” +Ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin Juda lọ bá Samsoni ní ibi ihò àpáta tí ó wà ní Etamu, wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé àwọn ará Filistia ni wọ́n ń ṣe àkóso wa ni? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí?”Ó dá wọn lóhùn pé, “Oró tí wọ́n dá mi ni mo dá wọn.” +Wọ́n dá a lóhùn pé, “A wá láti dì ọ́ tọwọ́ tẹsẹ̀ kí á sì gbé ọ lọ fún àwọn ará Filistia ni.”Samsoni dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ búra fún mi pé ẹ̀yin tìkara yín kò ní pa mí.” +Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá, àwa óo dì ọ́, a óo sì gbé ọ lé wọn lọ́wọ́ ni, a kò ní pa ọ́ rárá.” Wọ́n bá mú okùn titun meji, wọ́n fi dì í, wọ́n sì gbé e jáde láti inú ihò àpáta náà. +Nígbà tí ó dé Lehi, àwọn Filistia wá hó pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA bà lé Samsoni tagbára tagbára, okùn tí wọ́n fi dè é sì já bí ìgbà tí iná ràn mọ́ fọ́nrán òwú. Gbogbo ìdè tí wọ́n fi dè é já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀. +Ó rí egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹrun ninu àwọn ará Filistia. +Samsoni bá dáhùn pé,“Páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni mo fi pa wọ́n jọ bí òkítì,Egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni mo fi pa ẹgbẹrun eniyan.” +Lẹ́yìn tí ó wí báyìí tán, ó ju egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sílẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní Ramati Lehi. +Òùngbẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ ẹ́ gidigidi, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní, “Ìwọ ni o ran èmi iranṣẹ rẹ lọ́wọ́ láti ṣẹgun lónìí, ṣugbọn ṣé òùngbẹ ni yóo wá gbẹ mí pa, tí n óo fi bọ́ sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà wọnyi?” +Ọlọrun bá la ibi ọ̀gbun kan tí ó wà ní Lehi, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde láti inú ọ̀gbun náà. Lẹ́yìn tí ó mu omi tán, ojú rẹ̀ wálẹ̀, nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Enhakore. Enhakore yìí sì wà ní Lehi títí di òní olónìí. +Baba iyawo rẹ̀ wí fún un pé, “Mo rò pé lóòótọ́ ni o kórìíra iyawo rẹ, nítorí náà, mo ti fi fún ẹni tí ó jẹ́ ọrẹ rẹ tímọ́tímọ́, ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ. Ṣé ìwọ náà rí i pé àbúrò rẹ̀ lẹ́wà jù ú lọ, jọ̀wọ́ fẹ́ ẹ dípò rẹ̀.” +Samsoni ṣe aṣiwaju ní Israẹli ní àkókò àwọn Filistini fún ogún ọdún. +Samsoni dáhùn pé, “Bí mo bá ṣe àwọn ará Filistia ní ibi ní àkókò yìí, n kò ní jẹ̀bi wọn.” +Samsoni bá lọ, ó mú ọọdunrun (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láàyè, ó wá ìtùfù, ó sì so àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà ní ìrù pọ̀ ní meji meji, ó fi ìtùfù sí ààrin ìrù wọn. +Ó ṣáná sí àwọn ìtùfù náà, ó sì tú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà sílẹ̀ ninu oko ọkà àwọn ará Filistia. Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yìí bá tan iná ran gbogbo ìtí ọkà ati àwọn ọkà tí ó wà ní òòró ati gbogbo ọgbà olifi wọn; gbogbo wọn sì jóná ráúráú. +Àwọn ará Filistia bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ta ni ó dán irú èyí wò?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni, ọkọ ọmọ ará Timna ni; nítorí pé àna rẹ̀ fi iyawo rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Àwọn ará Filistia bá lọ dáná sun iyawo náà ati baba rẹ̀. +Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé bí ẹ óo ti ṣe nìyí n óo gbẹ̀san lára yín, lẹ́yìn náà, n óo fi yín sílẹ̀.” +Samsoni pa ọpọlọpọ ninu wọn. Ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ ń gbé inú ihò àpáta kan tí ó wà ní Etamu. +Àwọn ará Filistia bá kógun wá sí Juda, wọ́n sì kọlu ìlú Lehi. +Samsoni ní Ìlú Gasa. +Ní ọjọ́ kan, Samsoni lọ sí ìlú Gasa, ó rí obinrin aṣẹ́wó kan níbẹ̀, ó bá wọlé tọ̀ ọ́ lọ. +Delila tún wí fún Samsoni pé, “Ò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o sì ń purọ́ fún mi. Jọ̀wọ́ sọ bí eniyan ṣe le dè ọ́ lókùn fún mi.” +Ó dá a lóhùn pé, “Tí wọ́n bá fi okùn titun, tí wọn kò tíì lò rí dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.” +Delila bá mú okùn titun, ó fi dè é, ó sì wí fún un pé, “Samsoni, àwọn ará Filistia dé!” Àwọn tí wọ́n sápamọ́ sì wà ninu yàrá inú. Ṣugbọn Samsoni fa okùn náà já bí ẹni pé fọ́nrán òwú kan ni. +Delila tún wí fún Samsoni pé, “Sibẹsibẹ o ṣì tún ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o tún ń purọ́ fún mi. Sọ fún mi bí eniyan ṣe lè gbé ọ dè.”Ó dá a lóhùn pé, “Bí o bá di ìdì irun meje tí ó wà lórí mi, mọ́ igi òfì, tí o sì dì í papọ̀, yóo rẹ̀ mi, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.” +Nítorí náà, nígbà tí ó sùn, Delila mú ìdì irun mejeeje tí ó wà lórí rẹ̀, ó lọ́ ọ mọ́ igi òfì, ó sì fi èèkàn kàn án mọ́lẹ̀, ó bá pè é, ó ní, “Samsoni! Àwọn Filistini dé.” Ṣugbọn nígbà tí ó jí láti ojú oorun rẹ̀, ó fa èèkàn ati igi òfì náà tu. +Delila tún sọ fún un pé, “Báwo ni o ṣe lè wí pé o nífẹ̀ẹ́ mí, nígbà tí ọkàn rẹ kò sí lọ́dọ̀ mi. O ti fi mí ṣe ẹlẹ́yà nígbà mẹta, o kò sì sọ àṣírí agbára ńlá rẹ fún mi.” +Nígbà tí Delila bẹ̀rẹ̀ sí yọ ọ́ lẹ́nu lemọ́lemọ́, tí ó sì ń rọ̀ ọ́ lojoojumọ, ọ̀rọ̀ náà sú Samsoni patapata. +Ó bá tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún Delila, ó ní, “Ẹnìkan kò fi abẹ kàn mí lórí rí, nítorí pé Nasiri Ọlọrun ni mí láti inú ìyá mi wá. Bí wọ́n bá fá irun mi, agbára mi yóo fi mí sílẹ̀, yóo rẹ̀ mí n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.” +Nígbà tí Delila rí i pé ó ti tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún òun, ó ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, ó ní, “Ẹ tún wá lẹ́ẹ̀kan sí i, nítorí pé ó ti sọ gbogbo inú rẹ̀ fún mi.” Àwọn ọba Filistini maraarun bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n mú owó náà lọ́wọ́. +Delila mú kí Samsoni sùn lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó bá pe ọkunrin kan pé kí ó fá ìdì irun mejeeje tí ó wà ní orí Samsoni. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́ níyà, agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀. +Àwọn kan bá lọ sọ fún àwọn ará Gasa pé Samsoni wà níbẹ̀. Wọ́n yí ilé náà po, wọ́n sì ba dè é níbi ẹnu ọ̀nà bodè ìlú ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́, wọ́n ní, “Ẹ jẹ́ kí á dúró títí di ìdájí kí á tó pa á.” +Ó wí fún un pé, “Samsoni! Àwọn ará Filistia ti dé.” Samsoni bá jí láti ojú oorun, ó ní, “N óo lọ bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, n óo sì gba ara mi lọ́wọ́ wọn.” Kò mọ̀ pé OLUWA ti fi òun sílẹ̀. +Àwọn Filistini bá kì í mọ́lẹ̀, wọ́n yọ ojú rẹ̀, wọ́n mú un wá sí ìlú Gasa, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n idẹ dè é. Wọ́n ní kí ó máa lọ àgbàdo ninu ilé ẹ̀wọ̀n. +Ṣugbọn irun orí rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí kún lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a. +Ní ọjọ́ kan, àwọn ọba Filistini kó ara wọn jọ láti rú ẹbọ ńlá kan sí Dagoni, oriṣa wọn, ati láti ṣe àríyá pé oriṣa wọn ni ó fi Samsoni ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́. +Nígbà tí àwọn eniyan rí i, wọ́n yin oriṣa wọn; wọ́n ní, “Oriṣa wa ti fi ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́, ẹni tí ó sọ ilẹ̀ wa di ahoro tí ó sì pa ọpọlọpọ ninu wa.” +Nígbà tí inú wọn dùn, wọ́n ní, “Ẹ pe Samsoni náà wá, kí ó wá dá wa lára yá.” Wọ́n pe Samsoni jáde láti inú ilé ẹ̀wọ̀n, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá wọn lára yá. Wọ́n mú un lọ sí ààrin òpó mejeeji pé kí ó dúró níbẹ̀. +Samsoni bá bẹ ọdọmọkunrin tí ó mú un lọ́wọ́, ó ní, “Jẹ́ kí n fi ọwọ́ kan àwọn òpó tí gbogbo ilé yìí gbé ara lé kí n lè fara tì wọ́n.” +Ilé náà kún fún ọpọlọpọ eniyan, lọkunrin ati lobinrin; gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini ni wọ́n wà níbẹ̀. Lórí òrùlé nìkan, àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tó ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, lọkunrin ati lobinrin tí wọn ń wo Samsoni níbi tí ó ti ń dá wọn lára yá. +Samsoni bá ké pe OLUWA, ó ní, “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́, ranti mi, kí o sì fún mi lágbára lẹ́ẹ̀kan péré sí i, jọ̀wọ́ Ọlọrun mi, kí n lè gbẹ̀san lára àwọn Filistini fún ọ̀kan ninu ojú mi mejeeji.” +Samsoni bá gbá àwọn òpó mejeeji tí ó wà láàrin, tí ilé náà gbára lé mú, ó gbé ọwọ́ ọ̀tún lé ọ̀kan, ó gbé ọwọ́ òsì lé ekeji, ó sì fi gbogbo agbára rẹ̀ tì wọ́n. +Ṣugbọn Samsoni sùn títí di ọ̀gànjọ́ òru. Ní òru náà, ó gbéra, ó gbá ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà mú ati àwọn òpó rẹ̀ mejeeji, ó sì fà á tu pẹlu irin ìdábùú rẹ̀, ó gbé wọn lé èjìká, ó sì rù wọ́n lọ sí orí òkè kan tí ó wà ní iwájú Heburoni. +Ó wí pé, “Jẹ́ kí èmi náà kú pẹlu àwọn ará Filistia.” Ó bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu gbogbo agbára rẹ̀. Ilé náà sì wó lu gbogbo àwọn ọba Filistini ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu rẹ̀. Nítorí náà, iye eniyan tí ó pa nígbà tí òun náà yóo fi kú, ju àwọn tí ó pa nígbà tí ó wà láàyè lọ. +Àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ bá wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n lọ sin ín sáàrin Sora ati Eṣitaolu ninu ibojì Manoa, baba rẹ̀. Ogún ọdún ni ó fi ṣe aṣiwaju ní Israẹli. +Lẹ́yìn èyí, Samsoni rí obinrin kan tí ó wù ú ní àfonífojì Soreki, ó sì fẹ́ ẹ. Delila ni orúkọ obinrin náà. +Àwọn ọba Filistia wá sọ́dọ̀ obinrin yìí, wọ́n ní, “Tan ọkọ rẹ, kí o sì mọ àṣírí agbára rẹ̀, ati ọ̀nà tí a fi lè kápá rẹ̀; kí á lè dì í lókùn kí á sì ṣẹgun rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóo sì fún ọ ní ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka.” +Delila bá pe Samsoni, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ àṣírí agbára rẹ fún mi, ati bí eniyan ṣe lè so ọ́ lókùn kí eniyan sì kápá rẹ.” +Samsoni dá a lóhùn pé, “Bí wọ́n bá fi awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, tí kò tíì gbẹ meje dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.” +Àwọn ọba Filistini bá kó awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, titun, meje, tí kò tíì gbẹ, fún Delila, ó sì fi so Samsoni. +Ó ti fi àwọn eniyan pamọ́ sinu yàrá inú. Ó bá pe Samsoni, ó ní, “Samsoni àwọn ará Filistia dé.” Ṣugbọn Samsoni já awọ ọrun náà bí ìgbà tí iná já fọ́nrán òwú lásán. Wọn kò sì mọ àṣírí agbára rẹ̀. +Ère Mika. +Ọkunrin kan wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. +Mika bá sọ fún un pè, “Máa gbé ọ̀dọ̀ mi, kí o sì jẹ́ baba ati alufaa fún mi, n óo máa san owó fadaka mẹ́wàá fún ọ lọ́dún. N óo máa dáṣọ fún ọ, n óo sì máa bọ́ ọ.” +Ọdọmọkunrin ọmọ Lefi náà gbà, láti máa gbé ọ̀dọ̀ Mika. Mika sì mú un gẹ́gẹ́ bí ọmọ. +Mika fi ọdọmọkunrin náà jẹ alufaa, ó sì ń gbé ilé Mika. +Mika bá dáhùn pé, “Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo bukun mi, nítorí pé, ọmọ Lefi gan-an ni mo gbà gẹ́gẹ́ bí alufaa.” +Ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Wọ́n gbé ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka mọ́ ọ lọ́wọ́ nígbà kan, mo sì gbọ́ tí ò ń gbé ẹni tí ó gbé owó náà ṣépè, ọwọ́ mi ni owó náà wà, èmi ni mo gbé e.”Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “OLUWA yóo bukun ọ, ọmọ mi.” +Mika gbé ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka náà pada fún ìyá rẹ̀.Ìyá rẹ̀ bá dáhùn pé, “Mo ya fadaka náà sí mímọ́ fún OLUWA, kí ọmọ mi yá ère fínfín kan kí ó sì yọ́ fadaka náà lé e lórí. Nítorí náà, n óo dá a pada fún ọ.” +Nígbà tí Mika kó owó náà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ mú igba owó fadaka ninu rẹ̀, ó kó o fún alágbẹ̀dẹ fadaka láti yọ́ ọ sórí ère náà, wọ́n sì gbé ère náà sí ilé Mika. +Mika ní ojúbọ kan fún ara rẹ̀, ó dá ẹ̀wù funfun kan, ó sì ṣe àwọn ère kéékèèké. Ó fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe alufaa oriṣa rẹ̀. +Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, nítorí náà ohun tí ó bá tọ́ lójú olukuluku ni olukuluku ń ṣe. +Ọdọmọkunrin kan wà ní Juda, ará Bẹtilẹhẹmu, tí ó jẹ́ ọmọ Lefi láti inú ìdílé Juda, ó ń gbé ibẹ̀. +Ọdọmọkunrin náà kó kúrò ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda, láti lọ máa gbé ibikíbi tí ó bá ti rí ààyè. Bí ó ti ń lọ, ó dé ilé Mika ní agbègbè olókè ti Efuraimu. +Mika bá bi í pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”Ó dá a lóhùn pé, “Ọmọ Lefi, láti Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda ni mí, ibi tí n óo máa gbé ni mò ń wá kiri.” +Mika ati Ẹ̀yà Dani. +Ní àkókò kan, kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli, ati pé, ní àkókò náà, àwọn ẹ̀yà Dani ń wá ilẹ̀ tí wọn yóo gbà, tí wọn yóo sì máa gbé, nítorí pé, títí di àkókò yìí wọn kò tíì fún wọn ní ilẹ̀ kankan láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli. +Nígbà tí ẹ bá lọ, ẹ óo dé ibìkan tí àwọn eniyan ń gbé láìbẹ̀rù, ilẹ̀ náà tẹ́jú. Dájúdájú Ọlọrun ti fi lé yín lọ́wọ́, kò sí ohun tí eniyan ń fẹ́ ní ayé yìí tí kò sí níbẹ̀.” +Ẹgbẹta (600) ọkunrin ninu ẹ̀yà Dani tí wọ́n dira ogun gbéra láti Sora ati Eṣitaolu. +Wọ́n lọ pàgọ́ sí Kiriati Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Mahanedani títí di òní olónìí; ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn Kiriati Jearimu. +Wọ́n lọ láti ibẹ̀ sí agbègbè olókè ti Efuraimu, wọ́n dé ilé Mika. +Nígbà náà ni àwọn ọkunrin marun-un tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ Laiṣi sọ fún àwọn arakunrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ẹ̀wù efodu kan wà ninu àwọn ilé wọnyi ati àwọn ère kéékèèké, ati ère tí wọ́n gbẹ́ tí wọ́n sì yọ́ fadaka bò lórí, nítorí náà, kí ni ẹ rò pé ó yẹ kí á ṣe?” +Wọ́n bá yà sibẹ, wọ́n sì lọ sí ilé ọdọmọkunrin ọmọ Lefi, tí ó wà ní ilé Mika, wọ́n bèèrè alaafia rẹ̀. +Àwọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ará Dani tí wọ́n dira ogun dúró ní ẹnu ibodè. +Àwọn marun-un tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà bá wọlé, wọ́n gbé ère dídà, wọn mú ẹ̀wù efodu, wọ́n sì kó àwọn ère kéékèèké ati ère fínfín. Ọdọmọkunrin alufaa yìí sì wà ní ẹnu ibodè pẹlu àwọn ẹgbẹta (600) ọkunrin láti inú ẹ̀yà Dani tí wọ́n ti dira ogun. +Nígbà tí àwọn marun-un náà lọ sí ilé Mika tí wọ́n sì kó àwọn ère rẹ̀ ati àwọn nǹkan oriṣa rẹ̀, alufaa náà bi wọ́n léèrè pé, “Irú kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí?” +Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́, pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì tẹ̀lé wa, kí o jẹ́ baba ati alufaa fún wa. Èwo ni ìwọ náà rò pé ó dára jù; kí o jẹ́ alufaa fún ilé ẹnìkan ni tabi fún odidi ẹ̀yà kan ati ìdílé kan ní Israẹli?” +Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Dani rán akikanju marun-un láàrin àwọn eniyan wọn, láti ìlú Sora ati Eṣitaolu, kí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà kí wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n wí fún àwọn amí náà pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì yẹ ilẹ̀ náà wò.” Wọ́n bá gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè ti Efuraimu. Nígbà tí wọ́n dé ilé Mika, wọ́n wọ̀ sibẹ. +Inú alufaa náà bá dùn, ó gbé ẹ̀wù efodu, ó kó àwọn ère kékeré náà ati ère dídà náà, ó ń bá àwọn eniyan náà lọ. +Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n ń lọ. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati àwọn ẹrù wọn ń lọ níwájú wọn. +Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn jìnnà sí ilé Mika, Mika pe gbogbo àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dani bá. +Wọ́n kígbe pè wọ́n, àwọn ará Dani bá yipada, wọn bi Mika pé, “Kí ní ń dà ọ́ láàmú tí o fi ń bọ̀ pẹlu ọpọlọpọ eniyan báyìí?” +Ó bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ kó àwọn oriṣa mi, tí mo dà, ẹ mú alufaa mi lọ; kí ni ó kù mí kù. Ẹ tún wá ń bi mí pé, Kí ló ń ṣe mí?” +Àwọn ará Dani dá a lóhùn, wọ́n ní, “Má jẹ́ kí àwọn eniyan gbọ́ ohùn rẹ láàrin wa, kí àwọn tí inú ń bí má baà pa ìwọ ati gbogbo ìdílé rẹ.” +Àwọn ará Dani bá ń bá tiwọn lọ, nígbà tí Mika rí i pé wọ́n lágbára ju òun lọ, ó pada sílé rẹ̀. +Lẹ́yìn tí àwọn ará Dani ti kó oriṣa Mika, tí wọ́n sì ti gba alufaa rẹ̀, wọ́n lọ sí Laiṣi, wọ́n gbógun ti àwọn eniyan náà níbi t�� wọ́n jókòó sí jẹ́jẹ́ láì bẹ̀rù; wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì dáná sun ìlú wọn. +Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà wọ́n sílẹ̀, nítorí pé wọ́n jìnnà sí ìlú Sidoni, wọn kò sì bá ẹnikẹ́ni ní àyíká wọn da nǹkankan pọ̀. Àfonífojì Betirehobu ni ìlú Laiṣi yìí wà. Wọ́n tún un kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. +Wọ́n yí orúkọ ìlú náà pada kúrò ní Laiṣi tí ó ń jẹ́ tẹ́lẹ̀, wọ́n sọ ọ́ ní Dani gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Israẹli. +Nígbà tí wọ́n wà ní ilé Mika, wọ́n ṣàkíyèsí bí ọdọmọkunrin tí ó wà ní ilé Mika ṣe ń sọ̀rọ̀, wọ́n sì mọ̀ pé ọmọ Lefi ni. Wọ́n bá bi í pé, “Ta ló mú ọ wá síhìn-ín? Kí ni ò ń ṣe níhìn-ín? Kí sì ni iṣẹ́ rẹ?” +Àwọn ará Dani gbé ère dídà náà kalẹ̀ fún ara wọn. Jonatani ọmọ Geriṣomu, ọmọ Mose ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n jẹ́ alufaa fún àwọn ẹ̀yà Dani títí di àkókò tí wọ́n kó gbogbo agbègbè wọn ní ìgbèkùn. +Ère tí Mika yá ni wọ́n gbé kalẹ̀, ní gbogbo àkókò tí ilé Ọlọrun fi wà ní Ṣilo. +Ó dá wọn lóhùn pé, “Mika ti bá mi ṣètò, ó ti gbà mí gẹ́gẹ́ bí alufaa rẹ̀.” +Wọ́n bá bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, bá wa wádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun, kí á lè mọ̀ bóyá ìrìn àjò tí à ń lọ yìí yóo yọrí sí rere.” +Alufaa náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní alaafia, Ọlọrun fọwọ́ sí ìrìn àjò tí ẹ̀ ń lọ.” +Àwọn ọkunrin marun-un náà bá kúrò níbẹ̀, wọ́n wá sí Laiṣi, wọ́n sì rí àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀ bí wọ́n ti ń gbé ní àìléwu gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Sidoni tií máa ṣe. Wọ́n ń gbé pọ̀ ní alaafia, kò sí ìjà láàrin wọn, wọ́n ní ohun gbogbo tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ní ọrọ̀. Wọ́n rí i bí wọ́n ti jìnnà sí ibi tí àwọn ará Sidoni wà tó, ati pé wọn kò bá ẹnikẹ́ni da nǹkan pọ̀ ní gbogbo àyíká wọn. +Nígbà tí àwọn ọkunrin marun-un náà pada dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan wọn ní Sora ati Eṣitaolu, àwọn eniyan wọn bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni ọ̀hún ti rí?” +Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ gbógun tì wọ́n nítorí pé a ti rí ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tí ó lọ́ràá ni. Ẹ má jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀. Ẹ má jáfara, ẹ wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì gbà á. +Ọmọ Lefi Kan ati Obinrin Rẹ̀. +Ní àkókò tí kò sí ọba ní Israẹli, ọmọ Lefi kan ń gbé apá ibìkan tí ó jìnnà ní agbègbè olókè ti Efuraimu. Ọmọ Lefi yìí ní obinrin kan tí ó jẹ́ ará Bẹtilẹhẹmu ni ilẹ̀ Juda. +Ṣugbọn ọkunrin náà kọ̀, ó ní òun kò ní di ọjọ́ keji. Ó bá gbéra, ó ń lọ, títí tí wọ́n fi dé ibìkan tí ó dojú kọ Jebusi (tí wọ́n yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu); àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀, obinrin rẹ̀ sì wà pẹlu rẹ̀. +Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jebusi, ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, iranṣẹ rẹ̀ sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á dúró ní ìlú àwọn ará Jebusi yìí kí á sì sùn níbẹ̀ lónìí.” +Ó dá a lóhùn, ó ní, “A kò ní wọ̀ ní ìlú àjèjì, lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ọmọ Israẹli, kàkà bẹ́ẹ̀, a óo kọjá lọ sí Gibea.” +Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi, kí á sì sùn ní Gibea tabi ní Rama.” +Wọ́n bá tún ń bá ìrìn àjò wọn lọ, oòrùn ti wọ̀ kí wọ́n tó dé Gibea, ọ̀kan ninu àwọn ìlú ẹ̀yà Bẹnjamini. +Wọ́n yà sibẹ, láti sùn di ọjọ́ keji. Wọ́n lọ jókòó ní ààrin ìgboro ìlú náà, nítorí pé, ẹnikẹ́ni kò gbà wọ́n sílé pé kí wọ́n sùn di ọjọ́ keji. +Nígbà tí ó yá, ọkunrin arúgbó kan ń ti oko bọ̀ ní alẹ́; ará agbègbè olókè Efuraimu ni, ṣugbọn Gibea ni ó ń gbé. Àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ń gbé ìlú náà. +Bí ó ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn àlejò náà ní ìta gbangba láàrin ìgboro ìlú náà; ó sì bi wọ́n léèrè pé, “Níbo ni ẹ̀ ń lọ, níbo ni ẹ sì ti ń bọ̀?” +Ọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Láti Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni a ti ń bọ̀, a sì ń lọ sí ìgbèríko kan ní òpin agbègbè olókè Efuraimu níbi tí mo ti wá. Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni mo lọ, mo wá ń pada lọ sílé, nígbà tí a ti dé ìhín, kò sí ẹni tí ó gbà wá sílé. +Koríko tí a mú lọ́wọ́ tó fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa, oúnjẹ ati waini tí a sì mú lọ́wọ́ tó fún èmi ati iranṣẹbinrin rẹ ati ọdọmọkunrin tí ó wà pẹlu wa, ìyà ohunkohun kò jẹ wá.” +Èdè-àìyedè kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn mejeeji, obinrin yìí bá kúrò lọ́dọ̀ ọkunrin náà, ó lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu, ó sì ń gbé ibẹ̀ fún nǹkan bí oṣù mẹrin. +Baba arúgbó náà bá dáhùn pé, “Ṣé alaafia ni ẹ dé? Ẹ kálọ, n óo pèsè ohun gbogbo tí ẹ nílò fun yín, ẹ ṣá má sun ìta gbangba níhìn-ín.” +Baba náà bá mú wọn lọ sí ilé rẹ̀, ó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní koríko. Wọ́n ṣan ẹsẹ̀ wọn, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu. +Bí wọ́n ti ń gbádùn ara wọn lọ́wọ́ ni àwọn ọkunrin lásánlàsàn kan aláìníláárí, ará ìlú náà, bá yí gbogbo ilé náà po, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lu ìlẹ̀kùn. Wọ́n sọ fún baba arúgbó tí ó ni ilé náà pé, “Mú ọkunrin tí ó wọ̀ sinu ilé rẹ jáde, kí á lè bá a lòpọ̀.” +Baba arúgbó tí ó ni ilé yìí bá jáde sí wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ wọ́n, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ má hu irú ìwà burúkú báyìí, ṣé ẹ rí i pé ọkunrin yìí wá wọ̀ sinu ilé mi ni, ẹ má hu irú ìwà burúkú yìí sí i. +Mo ní ọmọbinrin kan tí ó jẹ́ wundia, ọkunrin náà sì ní obinrin kan, ẹ jẹ́ kí n mú wọn jáde sí yín nisinsinyii, kí ẹ sì ṣe wọ́n bí ẹ bá ti fẹ́, kí ẹ tẹ́ ìfẹ́ yín lọ́rùn lára wọn, ṣugbọn ẹ má ṣe hu irú ìwà burúkú yìí sí ọkunrin náà.” +Ṣugbọn àwọn ọkunrin náà kọ̀, wọn kò dá a lóhùn. Ó bá ki obinrin ọkunrin náà mọ́lẹ̀, ó tì í sí wọn lóde. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a lòpọ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, wọ́n fi sílẹ̀ pé kí ó máa lọ. +Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, obinrin yìí bá lọ wó lulẹ̀ sì ẹnu ọ̀nà baba arúgbó náà níbi tí ọkunrin tí ó mú un wá wà, ó wà níbẹ̀ títí tí ilẹ̀ fi mọ́ kedere. +Ọkunrin yìí bá dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ó ṣílẹ̀kùn ilé náà tí ó sì jáde pé kí òun máa lọ, òkú obinrin rẹ̀ ni ó rí, tí ó nà sílẹ̀ gbalaja lẹ́nu ọ̀nà, lẹ́bàá ìlẹ̀kùn, pẹlu ọwọ́ tí ó nà tí ó fẹ́ ṣílẹ̀kùn. +Ó pè é pé kí ó dìde kí àwọn máa lọ. Ṣugbọn obinrin yìí kò dá a lóhùn. Ó bá gbé òkú rẹ̀ nílẹ̀, ó gbé e sẹ́yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì lọ sílé rẹ̀. +Nígbà tí ó dé ilé, ó mú ọ̀bẹ, ó gé òkú obinrin yìí sí ọ̀nà mejila, ó sì fi wọ́n ranṣẹ sí gbogbo agbègbè Israẹli. +Lẹ́yìn náà, ọkọ rẹ̀ dìde, ó lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó pada. Ọkunrin yìí mú iranṣẹ kan ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bíi meji lọ́wọ́. Nígbà tí ó dé ilé baba obinrin rẹ̀ yìí, tí baba iyawo rẹ̀ rí i, ó lọ pàdé rẹ̀ tayọ̀tayọ̀. +Gbogbo àwọn tí wọ́n rí i sì ń wí pé, “A kò rí irú èyí rí láti ọjọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde láti ilẹ̀ Ijipti títí di àkókò yìí, ọ̀rọ̀ náà tó àpérò, ẹ gbìmọ̀ ohun tí a ó ṣe, kí ẹ sì sọ̀rọ̀.” +Baba obinrin náà rọ̀ ọ́ títí ó fi wà pẹlu wọn fún ọjọ́ mẹta; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì wà níbẹ̀. +Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu wọ́n fẹ́ máa lọ. Ṣugbọn baba ọmọbinrin náà rọ̀ ọ́ pé kí ó jẹ oúnjẹ díẹ̀ kí ó tó máa lọ, kí ó lè lágbára. +Àwọn ọkunrin mejeeji bá jókòó, wọ́n jẹ, wọ́n mu, lẹ́yìn náà ni baba ọmọbinrin yìí tún dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ kúkú dúró ní alẹ́ yìí kí o máa gbádùn ara rẹ.” +Nígbà tí ọkunrin náà gbéra, tí ó fẹ́ máa lọ, baba ọmọbinrin náà rọ̀ ọ́ títí tí ó tún fi dúró. +Nígbà tí ó di ọjọ́ karun-un, ọkunrin náà gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu láti máa lọ, baba ọmọbinrin náà tún rọ̀ ọ́ pé kí ó fọkàn balẹ̀, kí ó di ìrọ̀lẹ́ kí ó tó máa lọ. Àwọn mejeeji bá jọ jẹun. +Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́ ọkunrin náà ati obinrin rẹ̀ ati iranṣẹ rẹ̀ gbéra, wọ́n fẹ́ máa lọ; baba ọmọbinrin náà tún wí fún un pé, “Ṣé ìwọ náà rí i pè ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, jọ̀wọ́ dúró kí ó di ọ̀la. Ilẹ̀ ló ti ṣú yìí, dúró níhìn-ín kí o sì gbádùn ara rẹ, bí ó bá di ọ̀la kí ẹ bọ́ sọ́nà ní òwúrọ̀ kutukutu, kí ẹ sì máa lọ sílé.” +Angẹli OLUWA ní Bokimu. +Angẹli OLUWA gbéra láti Giligali, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ní Bokimu, ó sọ fún wọn pé, “Mo ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, wá sí ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá yín pé n óo fún wọn. Mo ní, ‘N kò ní yẹ majẹmu tí mo bá yín dá, +Gbogbo ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọ́n mọ OLUWA ati ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli patapata ni wọ́n kú, àwọn ìran mìíràn sì dìde lẹ́yìn wọn, wọn kò mọ OLUWA, ati gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli. +Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ oriṣa Baali. +Wọ́n kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn tí ó kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀, wọ́n ń bọ lára àwọn oriṣa àwọn tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n sì mú inú bí OLUWA. +Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọ́n ń bọ oriṣa Baali ati Aṣitarotu. +Inú bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó bá fi wọ́n lé àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà kan lọ́wọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jí wọn ní nǹkan kó. OLUWA tún fi wọ́n lé gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó wà ní àyíká wọn lọ́wọ́, apá wọn kò sì ká àwọn ọ̀tá wọn mọ́. +Nígbàkúùgbà tí wọ́n bá jáde lọ láti jagun, OLUWA á kẹ̀yìn sí wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti kìlọ̀ fún wọn tí ó sì búra fún wọn, ìdààmú a sì dé bá wọn. +Lẹ́yìn náà, OLUWA á gbé àwọn adájọ́ kan dìde, àwọn adájọ́ náà á sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà tí ń kó wọn ní nǹkan. +Sibẹsibẹ, wọn kì í gbọ́ ti àwọn aṣiwaju wọn. Wọn a máa sá lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa káàkiri, wọn a sì máa bọ wọ́n. Láìpẹ́ láìjìnnà, wọ́n á yipada kúrò ní ọ̀nà tí àwọn baba wọn ń rìn. Àwọn baba wọn a máa pa òfin OLUWA mọ́, ṣugbọn ní tiwọn àwọn kì í pa á mọ́. +Nígbàkúùgbà tí OLUWA bá gbé aṣiwaju kan dìde fún wọn, OLUWA a máa wà pẹlu aṣiwaju náà, a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, ní àkókò aṣiwaju náà. Ìkérora àwọn ọmọ Israẹli a máa mú kí àánú wọn ṣe OLUWA, nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá ń fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n sì ń ni wọ́n lára. +Ṣugbọn bí aṣiwaju yìí bá ti kú, kíá, wọn a tún ti yipada, wọn a sì tún ti máa ṣe ohun tí ó burú ju ohun tí àwọn baba wọn ti ṣe lọ. Wọn a máa lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọ́n a máa bọ wọ́n, wọn a sì máa foríbalẹ̀ fún wọn. Wọn kì í sì í fi ìṣe wọn ati oríkunkun wọn sílẹ̀. +ati pé, ẹ kò gbọdọ̀ bá èyíkéyìí ninu àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí dá majẹmu kankan, ẹ sì gbọdọ̀ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀.’ Ṣugbọn ẹ kò mú àṣẹ tí mo pa fun yín ṣẹ. Irú kí ni ẹ dánwò yìí? +Nítorí náà inú a bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, a sì wí pé, “Àwọn eniyan wọnyi ti da majẹmu tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba wọn, wọn kò sì fetí sí òfin mi. +Láti ìsinsìnyìí lọ n kò ní lé èyíkéyìí, ninu àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù kí Joṣua tó kú, jáde fún wọn. +Àwọn ni n óo lò láti wò ó bí àwọn ọmọ Israẹli yóo máa tọ ọ̀nà tí mo là sílẹ̀, bí àwọn baba ńlá wọn ti ṣe.” +Nítorí náà, OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀ náà, kò tètè lé wọn jáde bí kò ti fún Joṣua lágbára láti ṣẹgun wọn. +Nítorí náà, n kò ní lé wọn jáde fun yín mọ́; ṣugbọn wọn yóo di ọ̀tá yín, àwọn oriṣa wọn yóo sì di tàkúté fún yín.” +Nígbà tí Angẹli OLUWA sọ ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. +Ìdí nìyí tí wọ́n fi sọ orúkọ ibẹ̀ ní Bokimu, wọ́n sì rúbọ sí OLUWA níbẹ̀. +Nígbà tí Joṣua tú àwọn ọmọ Israẹli ká, olukuluku wọn pada lọ sí orí ilẹ̀ wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. +Àwọn eniyan náà sin OLUWA ní gbogbo àkókò tí Joṣua ati àwọn àgbààgbà tí wọ́n kù lẹ́yìn rẹ̀ wà láàyè, àwọn tí wọ́n fi ojú rí àwọn iṣẹ́ ńlá tí OLUWA ṣe fún Israẹli. +Joṣua, ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA, ṣaláìsí nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. +Wọ́n sì sin ín sórí ilẹ̀ rẹ̀ ní Timnati Sera, ní agbègbè olókè ti Efuraimu ní ìhà àríwá òkè Gaaṣi. +Israẹli Múra Ogun. +Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde wá, bẹ̀rẹ̀ láti Dani ní apá ìhà àríwá títí dé Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi, ní apá ìwọ̀ oòrùn. Wọ́n kó ara wọn jọ sójú kan ṣoṣo níwájú OLUWA ní Misipa. +Ìdámẹ́wàá àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli yóo máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun, àwọn yòókù yóo lọ jẹ àwọn ará Gibea níyà fún ìwà burúkú tí wọ́n hù ní Israẹli yìí.” +Gbogbo àwọn ọkunrin Israẹli bá kó ara wọn jọ, wọ́n gbógun ti ìlú náà. +Àwọn ọmọ Israẹli rán oníṣẹ́ jákèjádò ilẹ̀ Bẹnjamini, wọ́n ní, “Irú ìwà ìkà wo ni ẹ hù yìí? +Nítorí náà, ẹ kó àwọn aláìníláárí eniyan tí wọn ń hu ìwà ìkà ní Gibea jáde fún wa, kí á sì pa wọ́n, kí á mú ibi kúrò láàrin Israẹli.” Ṣugbọn àwọn ọmọ Bẹnjamini kò gba ohun tí àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Israẹli ń wí. +Àwọn ọmọ Bẹnjamini bá kó ara wọn jọ láti gbogbo ìlú ńláńlá, wọ́n wá sí Gibea láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli. +Àwọn ọmọ ogun tí àwọn ará Bẹnjamini kó jọ ní ọjọ́ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaata (26,000) àwọn ọkunrin tí wọn ń lo idà; láì ka àwọn tí wọn ń gbé Gibea tí àwọn náà kó ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin jọ. +Ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin tí wọn ń lo ọwọ́ òsì wà láàrin àwọn ọmọ ogun wọnyi. Wọ́n mọ kànnàkànnà ta, tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé wọ́n lè ta á mọ́ fọ́nrán òwú láì tàsé. +Láì ka àwọn tí àwọn ará Bẹnjamini náà kó jọ, àwọn ọmọ Israẹli kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) jagunjagun tí wọn ń lo idà jọ. +Àwọn ọmọ Israẹli gbéra lọ sí Bẹtẹli, wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun; ẹ̀yà tí yóo kọ́kọ́ gbógun ti ẹ̀yà Bẹnjamini.OLUWA dá wọn lóhùn pé ẹ̀yà Juda ni yóo kọ́kọ́ gbógun tì wọ́n. +Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, wọ́n lọ pàgọ́ sí òdìkejì Gibea, +Gbogbo àwọn olórí láàrin àwọn eniyan náà jákèjádò ilẹ̀ Israẹli kó ara wọn jọ pẹlu ìjọ eniyan Ọlọ́run. Àwọn ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn, tí wọ́n sì ń lo idà, tí wọ́n kó ara wọn jọ níbẹ̀ tàwọn ti idà lọ́wọ́ wọn jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ (400,000). +wọ́n bá gbógun ti àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini, wọ́n fi ìlú Gibea ṣe ojú ogun wọn. +Àwọn ará Bẹnjamini bá jáde sí wọn láti ìlú Gibea, wọ́n sì pa ọ̀kẹ́ kan (20,000) ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli ní ọjọ́ náà. +Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli mọ́kàn le, wọ́n tún gbógun tì wọ́n, wọ́n sì tún fi ibi tí wọ́n fi ṣe ojú ogun tẹ́lẹ̀ ṣe ojú ogun wọn. +Wọ́n bá lọ sọkún níwájú OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n ní, “Ṣé kí á tún gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tí í ṣe àwọn arakunrin wa?”OLUWA dá wọn lóhùn pé kí wọ́n lọ gbógun tì wọ́n. +Àwọn ọmọ Israẹli bá tún lọ gbógun ti àwọn ọmọ ogun Bẹnjamini ní ọjọ́ keji. +Àwọn ará Bẹnjamini bá tún jáde láti Gibea ní ọjọ́ keji, wọ́n pa ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) eniyan ninu àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń fi idà jà. +Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá lọ sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó wọ́n sọkún níbẹ̀ níwájú OLUWA, wọ́n gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú OLUWA. +Àwọn ọmọ Israẹli tún wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, nítorí pé àpótí majẹmu Ọlọrun wà ní Bẹtẹli ní àkókò náà. +Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni ló ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli tún bèèrè pé, “Ṣé kí á tún lọ gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tíí ṣe arakunrin wa àbí kí á dáwọ́ dúró?”OLUWA dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ lọ gbógun tì wọ́n, nítorí pé, lọ́la ni n óo fi wọ́n le yín lọ́wọ́.” +Àwọn ọmọ Israẹli bá fi àwọn eniyan pamọ́ ní ibùba, yípo gbogbo Gibea. +Àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti kó ara wọn jọ ní Misipa.Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ ọmọ Lefi náà pé, “Sọ fún wa, báwo ni nǹkan burúkú yìí ti ṣe ṣẹlẹ̀?” +Àwọn ọmọ Israẹli tún gbógun ti àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ kẹta, wọ́n tò yípo Gibea bíi ti iṣaaju. +Àwọn ará Bẹnjamini jáde sí wọn, àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí fi ọgbọ́n tàn wọ́n kúrò ní ìlú; àwọn ará Bẹnjamini tún bẹ̀rẹ̀ sí pa ninu àwọn ọmọ Israẹli bíi ti iṣaaju. Wọ́n pa wọ́n ní ojú òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí Bẹtẹli ati Gibea ati ninu pápá. Àwọn tí wọ́n pa ninu wọ́n tó ọgbọ̀n eniyan. +Àwọn ará Bẹnjamini wí fún ara wọn pé, “A tún ti tú wọn ká bíi ti iṣaaju.”Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá, kí á sì tàn wọ́n kúrò ninu ìlú wọn, kí wọ́n bọ́ sí ojú òpópó.” +Olukuluku àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò ní ààyè rẹ̀, wọ́n lọ tò ní Baalitamari. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ba ní ibùba bá jáde kúrò níbi tí wọ́n ba sí ní apá ìwọ̀ oòrùn Geba. +Ni ẹgbaarun (10,000) àṣàyàn àwọn jagunjagun ninu àwọn ọmọ Israẹli bá gbógun ti ìlú Gibea. Ogun náà gbóná gidigidi ṣugbọn àwọn ará Bẹnjamini kò mọ̀ pé ewu ńlá súnmọ́ tòsí wọn. +OLUWA bá ṣẹgun àwọn ará Bẹnjamini fún àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbẹẹdọgbọn ó lé ọgọrun-un (25,100) eniyan ninu àwọn ará Bẹnjamini lọ́jọ́ náà. Gbogbo àwọn tí wọ́n pa jẹ́ jagunjagun tí wọn ń lo idà. +Àwọn ọmọ Bẹnjamini rí i pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn. Nígbà tí, àwọn ọmọ Israẹli ṣebí ẹni ń sá lọ fún àwọn ara Bẹnjamini, wọ́n ń tàn wọ́n jáde ni, wọ́n sì ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ará wọn tí wọ́n ba ní ibùba yípo Gibea láti gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini. +Àwọn tí wọ́n ba ní ibùba yára jáde, wọ́n gbógun ti Gibea, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà run. +Àmì tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn tí wọ́n ba ní ibùba ti jọ ṣe fún ara wọn ni pé, nígbà tí wọ́n bá rí i tí èéfín ńlá yọ sókè ní Gibea, +kí àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti ń sá lọ yipada, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jagun. Àwọn ará Bẹnjamini ti pa bí ọgbọ̀n jagunjagun ninu àwọn Israẹli, wọ́n sì ti ń wí ninu ará wọn pé, “Dájúdájú a ti ṣẹgun wọn bíi ti àkọ́kọ́.” +Ọmọ Lefi, ọkọ obinrin tí wọ́n pa, bá dáhùn pé, “Èmi ati obinrin mi ni a yà sí Gibea ní ilẹ̀ àwọn ará Bẹnjamini pé kí á sùn níbẹ̀. +Ṣugbọn nígbà tí èéfín tí àwọn ọmọ ogun Israẹli fi ṣe àmì bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè láàrin ìlú, àwọn ará Bẹnjamini wo ẹ̀yìn, wọ́n rí i pé èéfín ti sọ, ó sì ti gba ìlú kan. +Àwọn ọmọ Israẹli bá yipada sí wọn, ìdààmú sì bá àwọn ọmọ Bẹnjamini nítorí wọ́n rí i pé ewu ńlá súnmọ́ tòsí. +Nítorí náà, wọ́n pada lẹ́yìn àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí ìhà aṣálẹ̀, ṣugbọn ọwọ́ bà wọ́n, nítorí pé ààrin àwọn jagunjagun tí wọ́n yipada sí wọn, ati àwọn tí wọn ń jáde bọ̀ láti inú ìlú ni wọ́n bọ́ sí. +Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n láì dáwọ́ dúró bí wọn ti ń lé wọn lọ. Wọ́n pa wọ́n láti Nohahi títí dé iwájú ìlà oòrùn Gibea. +Ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) ninu àwọn akikanju ará Bẹnjamini ni àwọn ọmọ Israẹli pa. +Wọ́n bá yipada, wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ tí ó lọ sí ibi àpáta Rimoni, àwọn ọmọ Israẹli sì tún pa ẹẹdẹgbaata (5,000) ninu wọn ní ojú ọ̀nà. Wọ́n ń lé wọn lọ tete títí dé Gidomu, wọ́n sì tún pa ẹgbaa (2,000) eniyan ninu wọn. +Gbogbo àwọn tí wọ́n kú ninu àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹẹdẹgbaata (25,000); gbogbo wọ́n jẹ́ akikanju jagunjagun tí ń lo idà. +Ṣugbọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ninu wọn sá lọ sí apá aṣálẹ̀, síbi àpáta Rimoni, wọ́n sì ń gbé inú àpáta Rimoni náà fún oṣù mẹrin. +Àwọn ọmọ Israẹli bá yipada sí àwọn ará Bẹnjamini, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo àwọn tí wọ́n bá fojú kàn, ati eniyan ati ẹranko. Gbogbo ìlú wọn tí wọ́n rí ni wọ́n sì sun níná. +Àwọn ọkunrin Gibea bá dìde lóru, wọ́n yí ilé tí mo wà po, wọ́n fẹ́ pa mí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá obinrin mi lòpọ̀ títí tí ó fi kú. +Mo bá gbé òkú rẹ̀, mo gé e lékìrí lékìrí, mo bá fi ranṣẹ sí gbogbo ilẹ̀ Israẹli jákèjádò, nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti ṣe nǹkan burúkú ati ohun ìríra ní Israẹli. +Gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gba ọ̀rọ̀ yí yẹ̀wò, kí ẹ sì mú ìmọ̀ràn yín wá lórí rẹ̀ nisinsinyii.” +Gbogbo àwọn eniyan náà bá fi ohùn ṣọ̀kan pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wa kò ní pada sí àgọ́ rẹ̀ tabi ilé rẹ̀. +Ohun tí a óo ṣe nìyí, gègé ni a óo ṣẹ́ láti mọ àwọn tí yóo gbógun ti Gibea. +Àwọn Ẹ̀yà Bẹnjamini Fẹ́ Iyawo. +Àwọn ọmọ Israẹli ti búra nígbà tí wọ́n wà ní Misipa pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wa kò ní fi ọmọ rẹ̀ fún ará Bẹnjamini.” +Ìjọ eniyan náà bá rán ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn jagunjagun wọn tí wọ́n gbójú jùlọ, wọ́n sì fún wọn láṣẹ pé, “Ẹ lọ fi idà pa gbogbo àwọn tí ń gbé Jabeṣi Gileadi ati obinrin wọn, ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn. +Ohun tí ẹ ó ṣe nìyí: gbogbo ọkunrin wọn ati gbogbo obinrin tí ó bá ti mọ ọkunrin, pípa ni kí ẹ pa wọ́n.” +Wọ́n rí irinwo (400) ọdọmọbinrin tí kò tíì mọ ọkunrin lára àwọn tí wọn ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì kó wọn wá sí àgọ́ ní Ṣilo, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani. +Ni ìjọ eniyan bá ranṣẹ sí àwọn ará Bẹnjamini tí wọ́n wà níbi àpáta Rimoni, pé ìjà ti parí, alaafia sì ti dé. +Nígbà náà ni àwọn ará Bẹnjamini tó pada wá, àwọn ọmọ Israẹli sì fún wọn ní àwọn obinrin tí wọ́n mú láàyè ninu àwọn obinrin Jabeṣi Gileadi, ṣugbọn àwọn obinrin náà kò kárí wọn. +Àánú àwọn ọmọ Bẹnjamini bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé OLUWA ti dín ọ̀kan kù ninu ẹ̀yà Israẹli. +Àwọn àgbààgbà ìjọ eniyan náà bá bèèrè pé, “Níbo ni a óo ti rí aya fún àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, níwọ̀n ìgbà tí a ti pa àwọn obinrin ẹ̀yà Bẹnjamini run.” +Wọ́n bá dáhùn pé, “Àwọn tí wọ́n kù ninu àwọn ara Bẹnjamini gbọdọ̀ ní ogún tiwọn, kí odidi ẹ̀yà kan má baà parun patapata ní Israẹli. +Ṣugbọn sibẹsibẹ, a kò gbọdọ̀ fi àwọn ọmọ wa fún wọn.” Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti búra pé, “Ẹni ègún ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọmọ fún ará Bẹnjamini.” +Wọ́n bá pinnu pé, “Ọdọọdún ni a máa ń ṣe àjọ̀dún OLUWA ní Ṣilo, tí ó wà ní apá àríwá Bẹtẹli, ní apá ìlà oòrùn òpópó ọ̀nà tí ó lọ láti Bẹtẹli sí Ṣekemu, ní apá gúsù Lebona.” +Àwọn eniyan bá wá sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó níwájú Ọlọrun títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì sọkún gidigidi. +Wọ́n bá fún àwọn ọkunrin Bẹnjamini láṣẹ pé, “Ẹ lọ ba ní ibùba ninu ọgbà àjàrà, +kí ẹ máa ṣọ́ àwọn ọmọbinrin Ṣilo bí wọ́n bá wá jó; ẹ jáde láti inú ọgbà àjàrà, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ki iyawo kọ̀ọ̀kan mọ́lẹ̀ ninu àwọn ọmọbinrin Ṣilo, kí ẹ sì gbé wọn sá lọ sí ilẹ̀ Bẹnjamini. +Nígbà tí àwọn baba wọn, tabi àwọn arakunrin wọn bá wá fi ẹjọ́ sùn wá, a óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún wọn nítorí pé àwọn obinrin tí a rí fún wọn ninu ogún kò kárí; kì í kúkú ṣe pé ẹ fi àwọn ọmọbinrin wọnyi fún wọn ni, tí ègún yóo fi ṣẹ le yín lórí.’ ” +Àwọn ará Bẹnjamini bá ṣe bí wọ́n ti sọ fún wọn. Olukuluku wọn gbé obinrin kọ̀ọ̀kan sá lọ ninu àwọn tí wọ́n wá jó, gbogbo wọn sì pada lọ sí ilẹ̀ wọn, wọ́n tún ìlú wọn kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. +Àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò níbẹ̀, gbogbo wọ́n sì pada sí ilẹ̀ wọn, olukuluku pada lọ sí ìlú rẹ̀, sí ààrin ẹbí rẹ̀. +Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, olukuluku bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ó ti tọ́ ní ojú ara rẹ̀. +Wọ́n wí pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí irú èyí fi ṣẹlẹ̀ ní Israẹli, tí ó fi jẹ́ pé lónìí ẹ̀yà Israẹli dín kan?” +Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, àwọn eniyan náà dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n tẹ́ pẹpẹ kan, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níbẹ̀. +Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè pé, “Èwo ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli ni kò wá sí ibi àjọ níwájú OLUWA?” Nítorí pé wọ́n ti ṣe ìbúra tí ó lágbára nípa ẹni tí kò bá wá siwaju OLUWA ní Misipa, wọ́n ní, “Pípa ni a óo pa á.” +Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí káàánú àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini arakunrin wọn, wọ́n ní, “Ẹ̀yà Israẹli dín kan lónìí. +Báwo ni a óo ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù; nítorí pé a ti fi OLUWA búra pé a kò ní fi àwọn ọmọbinrin wa fún wọn?” +Wọ́n bá bèèrè pé, “Ẹ̀yà wo ninu Israẹli ni kò wá siwaju OLUWA ní Misipa?” Wọ́n rí i pé ẹnikẹ́ni kò wá ninu àwọn ará Jabeṣi Gileadi sí àjọ náà. +Nítorí pé nígbà tí àwọn eniyan náà kó ara wọn jọ, ẹnikẹ́ni láti inú àwọn tí ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi kò sí níbẹ̀. +Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Ó Ṣẹ́kù lórí Ilẹ̀ Kenaani. +OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi sílẹ̀ láti fi dán Israẹli wò, pàápàá jùlọ, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọn kò tíì ní ìrírí ogun jíjà ní ilẹ̀ Kenaani. +Ẹ̀mí OLUWA bà lé e, ó sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Ó jáde lọ sí ojú ogun, OLUWA sì fi Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọ́wọ́, ó sì ṣẹgun rẹ̀. +Nítorí náà, ilẹ̀ náà wà ní alaafia fún ogoji ọdún, lẹ́yìn náà, Otinieli ọmọ Kenasi ṣaláìsí. +Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fún Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu, lágbára lórí wọn, nítorí pé wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. +Egiloni yìí kó àwọn ará Amoni ati àwọn ará Amaleki sòdí, wọ́n lọ ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì gba Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ, lọ́wọ́ wọn. +Àwọn ọmọ Israẹli sin Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu, fún ọdún mejidinlogun. +Ṣugbọn nígbà tí wọ́n tún ké pe OLUWA, OLUWA gbé olùdáǹdè kan, ọlọ́wọ́ òsì, dìde, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ehudu, ọmọ Gera, ará Bẹnjamini. Ní àkókò kan àwọn ọmọ Israẹli fi ìṣákọ́lẹ̀ rán an sí Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu. +Ehudu rọ idà olójú meji kan tí kò gùn ju igbọnwọ kan lọ, ó fi bọ inú àkọ̀, ó so ó mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún lábẹ́ aṣọ. +Ó fi ìṣákọ́lẹ̀ náà jíṣẹ́ fún Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu. Egiloni yìí jẹ́ ẹni tí ó sanra rọ̀pọ̀tọ̀. +Nígbà tí Ehudu fi ìṣákọ́lẹ̀ náà jíṣẹ́ tán, ó ní kí àwọn tí wọ́n rù ú máa pada lọ. +Òun nìkan bá pada ní ibi òkúta tí wọ́n gbẹ́, tí ó wà lẹ́bàá Giligali, ó tọ ọba lọ, ó ní, “Kabiyesi, mo ní iṣẹ́ àṣírí kan tí mo fẹ́ jẹ́ fún ọ.”Ọba bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rè�� tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n jáde, gbogbo wọn sì jáde. +Kí àwọn ọmọ Israẹli lè mọ̀ nípa ogun jíjà, pataki jùlọ, ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọn kò mọ̀ nípa ogun jíjà tẹ́lẹ̀. +Ehudu bá tọ̀ ọ́ lọ, níbi tí òun nìkan jókòó sí ninu yàrá tútù kan, lórí òrùlé ilé rẹ̀, ó wí fún un pé, “Ọlọ́run rán mi ní iṣẹ́ kan sí ọ,” ọba bá dìde níbi tí ó jókòó sí. +Ehudu bá fi ọwọ́ òsì fa idà tí ó so mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún yọ, ó sì tì í bọ ọba Egiloni níkùn. +Idà yìí wọlé tèèkùtèèkù, ọ̀rá sì padé mọ́ ọn, nítorí pé kò fa idà náà yọ kúrò ní ikùn ọba, ìfun ọba sì tú jáde. +Ehudu bá jáde, ó sì fi kọ́kọ́rọ́ ti gbogbo ìlẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà. +Lẹ́yìn tí ó ti sá lọ ni àwọn iranṣẹ ọba pada dé. Nígbà tí wọn rí i pé wọ́n ti fi kọ́kọ́rọ́ ti gbogbo ìlẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà, wọ́n rò ninu ara wọn pé, bóyá ọba wà ninu ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tí ó wà ninu yàrá orí òrùlé náà ni. +Wọ́n dúró títí tí agara fi dá wọn. Ṣugbọn nígbà tí ó kọ̀ tí kò ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n bá mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n ṣí àwọn ìlẹ̀kùn; wọ́n bá bá òkú oluwa wọn nílẹ̀. +Ní gbogbo ìgbà tí àwọn iranṣẹ wọnyi ń dúró pé kí ọba ṣílẹ̀kùn, Ehudu ti sá lọ, ó sì ti kọjá òkúta gbígbẹ́ tí ó wà lẹ́bàá Giligali, ó ti sá dé Seira. +Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọn fèrè ní agbègbè olókè Efuraimu. Àwọn ọmọ Israẹli bá tẹ̀lé e lẹ́yìn láti agbègbè olókè, ó sì ṣiwaju wọn. +Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí pé OLUWA ti fi àwọn ará Moabu, tíí ṣe ọ̀tá yín le yín lọ́wọ́.” Wọ́n bá ń tẹ̀lé e lọ, wọ́n gba ibi tí ó ṣe é fi ẹsẹ̀ là kọjá níbi odò Jọdani mọ́ àwọn ará Moabu lọ́wọ́, wọn kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá. +Wọ́n pa àwọn alágbára ati akikanju bí ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ará Moabu, kò sì sí ẹnìkan tí ó là ninu wọn. +Àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA fi sílẹ̀ nìwọ̀nyí: àwọn olú-ìlú Filistini maraarun ati gbogbo ilẹ̀ Kenaani, àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Hifi tí wọn ń gbé òkè Lẹbanoni, láti òkè Baali Herimoni títí dé ẹnubodè Hamati. +Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe ṣẹgun wọn ní ọjọ́ náà, ilẹ̀ náà sì wà ní alaafia fún ọgọrin ọdún. +Aṣiwaju tí ó tún dìde lẹ́yìn Ehudu ni Ṣamgari, ọmọ Anati, ẹni tí ó fi ọ̀pá tí wọ́n fi ń da mààlúù pa ẹgbẹta (600) ninu àwọn ará Filistia; òun náà gba Israẹli kalẹ̀. +Àwọn ni OLUWA fi dán àwọn ọmọ Israẹli wò, láti wò ó bóyá wọn óo mú àṣẹ tí òun pa fún àwọn baba wọn láti ọwọ́ Mose ṣẹ, tabi wọn kò ní mú un ṣẹ. +Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ààrin àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi. +Àwọn ọmọ Israẹli ń fẹ́mọ lọ́wọ́ àwọn eniyan orílẹ̀-èdè náà, àwọn náà ń fi ọmọ fún wọn; àwọn ọmọ Israẹli sì ń bọ àwọn oriṣa wọn. +Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa Baali ati Aṣerotu. +Nítorí náà, inú bí OLUWA sí wọn, ó sì fi wọ́n lé Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lọ́wọ́; wọn sì sìn ín fún ọdún mẹjọ. +Ṣugbọn nígbà tí wọ́n kígbe pé OLUWA, OLUWA gbé olùdáǹdè kan dìde fún wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, òun ni ó gbà wọ́n kalẹ̀. +Debora ati Baraki. +Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA lẹ́yìn ikú Ehudu. +Baraki bá pe àwọn ọmọ Sebuluni ati Nafutali sí Kedeṣi; ẹgbaarun (10,000) ọkunrin ninu wọn ni wọ́n tẹ̀lé Baraki, Debora náà sì bá wọn lọ. +Ní àkókò yìí, Heberi ará Keni ti kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ará Keni yòókù tí wọ́n jẹ́ ìran Hobabu, àna Mose, ó sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Kedeṣi lẹ́bàá igi oaku kan ní Saananimu. +Nígbà tí Sisera gbọ́ pé Baraki ti lọ sí orí òkè Tabori, +ó kó ẹẹdẹgbẹrun (900) kẹ̀kẹ́ ogun onírin rẹ̀ jọ, ó sì pe àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti Haroṣeti-ha-goimu títí dé odò Kiṣoni. +Debora wí fún Baraki pé, “Dìde nítorí pé òní ni ọjọ́ tí OLUWA yóo fi Sisera lé ọ lọ́wọ́. Ṣebí OLUWA ni ó ń ṣáájú ogun rẹ lọ?” Baraki bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Tabori pẹlu ẹgbaarun (10,000) ọmọ ogun lẹ́yìn rẹ̀. +OLUWA mú ìdàrúdàpọ̀ bá Sisera ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ níwájú Baraki. Bí àwọn ọmọ ogun Baraki ti ń fi idà pa wọ́n, Sisera sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. +Baraki lépa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun Sisera títí dé Haroṣeti-ha-goimu, wọ́n sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun Sisera láìku ẹyọ ẹnìkan. +Ṣugbọn Sisera sá lọ sí àgọ́ Jaeli, aya Heberi, ará Keni, nítorí pé alaafia wà ní ààrin Jabini, ọba Hasori, ati ìdílé Heberi ará Keni. +Jaeli bá jáde lọ pàdé Sisera, ó wí fún un pé, “Máa bọ̀ níhìn-ín, oluwa mi. Yà wá sọ́dọ̀ mi, má bẹ̀rù.” Sisera bá yà sinu àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ tí ó nípọn bò ó. +Sisera bá bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ òùngbẹ ń gbẹ mí, fún mi lómi mu.” Jaeli bá ṣí ìdérí ìgò tí wọ́n fi awọ ṣe, tí wọ́n da wàrà sí, ó fún un ní wàrà mu, ó sì tún da aṣọ bò ó. +OLUWA bá fi wọ́n lé Jabini ọba Kenaani, tí ó jọba ní Hasori lọ́wọ́; Sisera, tí ń gbé Haroṣeti-ha-goimu ni olórí ogun rẹ̀. +Sisera wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá wá, tí ó sì bi ọ́ léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wà níbí?’ Wí fún olúwarẹ̀ pé, ‘Kò sí.’ ” +Ó ti rẹ Sisera tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi sùn lọ fọnfọn. Jaeli bá mú òòlù kan, ati èèkàn àgọ́, ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Sisera sùn sí, ó kan èèkàn náà mọ́ ọn lẹ́bàá etí títí tí èèkàn náà fi wọlé, ó sì kú. +Bí Baraki ti ń wá Sisera kiri, Jaeli lọ pàdé rẹ̀, ó wí fún un pé, “Máa bọ̀ níhìn-ín, n óo sì fi ẹni tí ò ń wá hàn ọ́.” Baraki bá bá a wọlé lọ, ó sì bá Sisera nílẹ̀ níbi tí ó kú sí, pẹlu èèkàn àgọ́ tí wọn gbá mọ́ ọn lẹ́bàá etí. +Ní ọjọ́ náà ni Ọlọrun bá àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun Jabini, ọba àwọn ará Kenaani. +Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kọlu Jabini, ọba Kenaani lemọ́lemọ́ títí wọ́n fi pa á run. +Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA pé kí ó ran àwọn lọ́wọ́, nítorí pé ẹẹdẹgbẹrun (900) ni kẹ̀kẹ́ ogun Jabini tí wọ́n fi irin ṣe; ó sì ni wọ́n lára fún ogún ọdún. +Wolii obinrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Debora aya Lapidotu, ni adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli nígbà náà. +Lábẹ́ ọ̀pẹ kan, tí wọ́n sọ ní ọ̀pẹ Debora, tí ó wà láàrin Rama ati Bẹtẹli ní agbègbè olókè ti Efuraimu ní í máa ń jókòó sí, ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tií máa ń lọ bá a fún ìdájọ́. +Ó ranṣẹ pe Baraki, ọmọ Abinoamu, ní Kedeṣi, tí ó wà ní Nafutali, ó wí fún un pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ń pàṣẹ fún ọ pé kí o lọ kó àwọn eniyan rẹ̀ jọ ní òkè Tabori. Kó ẹgbaarun (10,000) eniyan ninu ẹ̀yà Nafutali ati Sebuluni jọ. +N óo ti Sisera olórí ogun Jabini jáde láti pàdé rẹ lẹ́bàá odò Kiṣoni pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, n óo sì fà á lé ọ lọ́wọ́.” +Baraki bá dá a lóhùn pé, “Bí o óo bá bá mi lọ ni n óo lọ, bí o kò bá ní bá mi lọ, n kò ní lọ.” +Debora dáhùn pé, “Láìṣe àní àní, n óo bá ọ lọ. Ṣugbọn ṣá o, ohun tí o fẹ́ ṣe yìí kò ní já sí ògo fún ọ, nítorí pé, OLUWA yóo fi Sisera lé obinrin kan lọ́wọ́.” Debora bá gbéra, ó bá Baraki lọ sí Kedeṣi. +Orin Debora ati Baraki. +Debora ati Baraki ọmọ Abinoamu bá kọrin ní ọjọ́ náà pé: +Ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jókòó lórí ẹní olówó iyebíye,ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ rìn. +Ẹ tẹ́tí sí ohùn àwọn akọrin lẹ́bàá odò,ibẹ̀ ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́gun OLUWA,ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun àwọn eniyan rẹ̀ ní Israẹli.Àwọn eniyan OLUWA sì yan jáde láti ẹnubodè ìlú wọn. +Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀! Debora!Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀, kí o dárin!Dìde, Baraki, máa kó àwọn tí o kó lógun lọ,ìwọ ọmọ Abinoamu! +Àwọn akikanju yòókù bẹ̀rẹ̀ sí yan bọ̀,àwọn eniyan OLUWA náà sì ń wọ́ bọ̀,láti gbógun ti alágbára. +Wọ́n gbéra láti Efuraimu lọ sí àfonífojì náà,wọ́n tẹ̀lé ọ, ìwọ Bẹnjamini pẹlu àwọn eniyan rẹ.Àwọn ọ̀gágun wá láti Makiri,àwọn olórí ogun sì wá láti Sebuluni. +Àwọn ìjòyè Isakari náà bá Debora wá,àwọn ọmọ Isakari jẹ́ olóòótọ́ sí Baraki,wọ́n sì dà tẹ̀lé e lẹ́yìn lọ sí àfonífojì.Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì,ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá. +Kí ló dé tí o fi dúró lẹ́yìn láàrin àwọn agbo aguntan?Tí o fi ń gbọ́ bí àwọn olùṣọ́-aguntan ti ń fọn fèrè fún àwọn aguntan wọn.Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì,ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá. +Àwọn ará Gileadi dúró ní ìlà oòrùn odò Jọdani,kí ló dé tí ẹ̀yà Dani fi dúró ní ìdí ọkọ̀ ojú omi?Àwọn ẹ̀yà A���eri jókòó létí òkun,wọ́n wà ní ẹsẹ̀ odò. +Àwọn ọmọ Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu dójú ikú,bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ọmọ Nafutali,wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn wéwu ninu pápá, lójú ogun. +“Ní Taanaki lẹ́bàá odò Megidoàwọn ọba wá, wọ́n jagun,wọ́n bá àwọn ọba Kenaani jagun,ṣugbọn wọn kò rí ìkógun fadaka kó. +Ẹ fi ìyìn fún OLUWA,nítorí pé, àwọn olórí ni wọ́n ṣiwaju ní Israẹli,àwọn eniyan sì fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀. +Láti ojú ọ̀run ni àwọn ìràwọ̀ ti ń jagun,àní láti ààyè wọn lójú ọ̀nà wọn,ni wọ́n ti bá Sisera jà. +Odò Kiṣoni kó wọn lọ,odò Kiṣoni, tí ó kún àkúnya.Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, máa fi agbára yan lọ. +Àwọn ẹṣin sáré dé, pẹlu ariwo pátákò ẹsẹ̀ wọn,wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹsẹ̀ kilẹ̀.” +Angẹli OLUWA ní, “Ìlú ègún ni ìlú Merosi,ẹni ègún burúkú sì ni àwọn olùgbé rẹ̀,nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò wá ran OLUWA lọ́wọ́;wọn kò ran OLUWA lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn alágbára.” +Ẹni ibukun jùlọ ni Jaeli láàrin àwọn obinrin,Jaeli, aya Heberi, ọmọ Keni,ẹni ibukun jùlọ láàrin àwọn obinrin tí ń gbé inú àgọ́. +Omi ni Sisera bèèrè, wàrà ni Jaeli fún un,àwo tí wọ́n fi ń gbé oúnjẹ fún ọbani ó fi gbé e fún un mu. +Ó na ọwọ́ mú èèkàn àgọ́,ó na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó he òòlù àwọn alágbẹ̀dẹ,ó kan Sisera mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo;ó fọ́ ọ lórí,ó lù ú ní ẹ̀bá etí,ó sì fọ́ yángá-yángá. +Sisera wó, ó ṣubú lulẹ̀,ó nà gbalaja lẹ́sẹ̀ Jaeli,ó wó lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú lulẹ̀.Ibi tí ó wó sí, náà ni ó sì kú sí. +Ìyá Sisera ń yọjú láti ojú fèrèsé,ó bẹ̀rẹ̀ sí wo ọ̀nà láti ibi ihò fèrèsé.Ó ní, “Kí ló dé tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó dé?Kí ló dé tí ó fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí á tó gbúròó ẹsẹ̀ àwọn ẹṣintí wọ́n ń wọ́ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀?” +Àwọn ọlọ́gbọ́n jùlọ ninu àwọn obinrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ dá a lóhùn,òun náà sì ń wí fún ara rẹ̀ pé, +Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọba;ẹ tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ìjòyè;OLUWA ni n óo kọrin sí,n óo kọrin dídùn sí OLUWA, Ọlọrun Israẹli. +“Ṣebí ìkógun ni wọ́n ń wá, tí wọ́n sì ń pín?Obinrin kan tabi meji fún ọkunrin kọ̀ọ̀kan,ìkógun àwọn aṣọ aláró fún Sisera,ìkógun àwọn aṣọ aláró tí wọ́n dárà sí lára,aṣọ ìborùn aláró meji tí wọ́n dárà sí lára fún èmi náà?” +Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ṣègbé, OLUWA;ṣugbọn bí oòrùn ti máa ń fi agbára rẹ̀ ràn,bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa tàn.Ilẹ̀ náà sì wà ní alaafia fún ogoji ọdún. +OLUWA, nígbà tí o jáde lọ láti òkè Seiri,nígbà tí o jáde lọ láti agbègbè Edomu,ilẹ̀ mì tìtì,omi bẹ̀rẹ̀ sí bọ́,ọ̀wààrà òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. +Àwọn òkè mì tìtì níwájú rẹ, OLUWA, àní, ní òkè Sinai níwájú OLUWA, Ọlọrun Israẹli. +Ní ìgbà ayé Ṣamgari, ọmọ Anati,ati nígbà ayé Jaeli, ọ̀wọ́ èrò kò rin ilẹ̀ yìí mọ́,àwọn arìnrìnàjò sì ń gba ọ̀nà kọ̀rọ̀. +Gbogbo ìlú dá wáí ní Israẹli, ó dá,gbogbo ìlú di àkọ̀tì,títí tí ìwọ Debora fi dìde,bí ìyá, ní Israẹli. +Ní gbogbo ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli dá oriṣa titun,ogun bo gbogbo ẹnubodè.Ninu bí ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli,ǹjẹ́ a rí ẹnikẹ́ni tí ó ní apata tabi ọ̀kọ̀? +Ọkàn mi lọ sọ́dọ̀ àwọn balogun Israẹli,tí wọ́n fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀ láàrin àwọn eniyan.Ẹ fi ìyìn fún OLUWA. +Gideoni. +Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́ fún ọdún meje. +Mo kìlọ̀ fún yín pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, ati pé ẹ kò gbọdọ̀ bọ oriṣa àwọn ará Amori tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ wọn, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ tèmi.’ ” +Angẹli OLUWA kan wá, ó jókòó lábẹ́ igi Oaku tí ó wà ní Ofira, igi Oaku yìí jẹ́ ti Joaṣi, ará Abieseri. Bí Gideoni ọmọ Joaṣi, ti ń pa ọkà ní ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí, tí ó ń fi í pamọ́ fún àwọn ará Midiani, +ni angẹli OLUWA náà yọ sí i, ó sì wí fún un pé, “OLUWA wà pẹlu rẹ, ìwọ akikanju ati alágbára ọkunrin.” +Gideoni dá a lóhùn, ó ní “Jọ̀wọ́, oluwa mi, bí OLUWA bá wà pẹlu wa, kí ló dé tí gbogbo nǹkan wọnyi fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbo sì ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu OLUWA wà, tí àwọn baba wa máa ń sọ fún wa nípa rẹ̀, pé, ‘Ṣebí OLUWA ni ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti?’ Ṣugbọn nisinsinyii OLUWA ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.” +Ṣugbọn OLUWA yipada sí i, ó sì dá a lóhùn pé, “Lọ pẹlu agbára rẹ yìí, kí o sì gba Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani, ṣebí èmi ni mo rán ọ.” +Gideoni dáhùn, ó ní, “Sọ fún mi OLUWA, báwo ni mo ṣe lè gba Israẹli sílẹ̀? Ìran mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Manase, èmi ni mo sì kéré jù ní ìdílé wa.” +OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “N óo wà pẹlu rẹ, o óo sì run àwọn ará Midiani bí ẹni pé, ẹyọ ẹnìkan péré ni wọ́n.” +Gideoni tún dáhùn, ó ní, “Bí inú rẹ bá yọ́ sí mi, fi àmì kan hàn mí pé ìwọ OLUWA ni ò ń bá mi sọ̀rọ̀. +Jọ̀wọ́, má kúrò níhìn-ín títí tí n óo fi mú ẹ̀bùn mi dé, tí n óo sì gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ.”Angẹli náà dá Gideoni lóhùn, ó ní, “N óo dúró títí tí o óo fi pada dé.” +Gideoni bá wọlé lọ, ó tọ́jú ọmọ ewúrẹ́ kan, ó sì fi ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Ó kó ẹran tí ó sè sinu agbọ̀n kan, ó da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sinu ìkòkò kan, ó gbé e tọ Angẹli OLUWA náà lọ ní abẹ́ igi Oaku, ó sì gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀. +Àwọn ará Midiani lágbára ju àwọn ọmọ Israẹli lọ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli fi ṣe ibi tí wọn ń sápamọ́ sí lórí àwọn òkè, ninu ihò àpáta, ati ibi ààbò mìíràn ninu òkè. +Angẹli Ọlọrun náà wí fún un pé, “Da ẹran náà ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ náà lé gbogbo rẹ̀ lórí.” Gideoni sì ṣe bẹ́ẹ̀. +Angẹli OLUWA náà bá na ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi ṣóńṣó orí rẹ̀ kan ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà; iná bá ṣẹ́ lára àpáta, ó sì jó ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà. Angẹli OLUWA náà bá rá mọ́ ọn lójú. +Nígbà náà ni Gideoni tó mọ̀ pé angẹli OLUWA ni, ó bá dáhùn pé, “Yéè! OLUWA Ọlọrun, mo gbé! Nítorí pé mo ti rí angẹli OLUWA lojukooju.” +Ṣugbọn OLUWA dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, má bẹ̀rù, o kò ní kú.” +Gideoni bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA, ó pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni Alaafia.” Pẹpẹ náà wà ní Ofira ti ìdílé Abieseri títí di òní olónìí. +Ní òru ọjọ́ náà, OLUWA sọ fún Gideoni pé, “Mú akọ mààlúù baba rẹ ati akọ mààlúù mìíràn tí ó jẹ́ ọlọ́dún meje, wó pẹpẹ oriṣa Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. +Kí o wá tẹ́ pẹpẹ kan fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ lórí òkítì ibi gegele náà. To àwọn òkúta rẹ̀ lérí ara wọn dáradára, lẹ́yìn náà mú akọ mààlúù keji kí o sì fi rú ẹbọ sísun. Igi ère oriṣa Aṣera tí o bá gé lulẹ̀ ni kí o fi ṣe igi ẹbọ sísun náà.” +Gideoni mú mẹ́wàá ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLUWA ti ní kí ó ṣe, ṣugbọn kò lè ṣe é lọ́sàn-án, nítorí ẹ̀rù àwọn ará ilé ati àwọn ará ìlú rẹ̀ ń bà á, nítorí náà lóru ni ó ṣe é. +Nígbà tí àwọn ará ìlú náà jí ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n rí i pé, wọ́n ti wó pẹpẹ oriṣa Baali lulẹ̀, wọ́n sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ati pé wọ́n ti fi mààlúù keji rúbọ lórí pẹpẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́. +Wọ́n bá ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ló dán irú èyí wò?” Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti wádìí, wọ́n ní, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.” +Nítorí pé, nígbàkúùgbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá gbin ohun ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Midiani ati àwọn ará Amaleki ati àwọn kan láti inú aṣálẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, a máa kó ara wọn jọ, wọn a lọ ṣígun bá àwọn ọmọ Israẹli. +Àwọn ará ìlú náà bá wí fún Joaṣi pé, “Mú ọmọ rẹ jáde kí á pa á, nítorí pé ó ti wó pẹpẹ oriṣa Baali, ó sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.” +Ṣugbọn Joaṣi dá àwọn tí wọ́n dìde sí Gideoni lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ gbèjà oriṣa Baali ni, àbí ẹ fẹ́ dáàbò bò ó? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèjà rẹ̀, pípa ni a óo pa á kí ilẹ̀ tó mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé ọlọrun ni Baali nítòótọ́, kí ó gbèjà ara rẹ̀, nítorí pẹpẹ rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.” +Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti ń pe Gideoni ní Jerubaali, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ẹ jẹ́ kí Baali bá a jà fúnra rẹ̀,” nítorí pé ó wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀. +Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati àwọn ará ilẹ̀ Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn kó ara wọn jọ, wọ́n la odò Jọdani kọjá, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí àfonífojì Jesireeli. +Ṣugbọn Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Gideoni, Gideoni bá fọn fèrè ogun, àwọn ọm�� Abieseri bá pe ara wọn jáde wọ́n bá tẹ̀lé e. +Ó ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Manase, wọ́n pe ara wọn jáde, wọ́n sì tẹ̀lé e. Ó tún ranṣẹ bákan náà sí ẹ̀yà Aṣeri, ẹ̀yà Sebuluni, ati ẹ̀yà Nafutali, àwọn náà sì lọ pàdé rẹ̀. +Gideoni wí fún Ọlọrun pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni o fẹ́ lò láti gba Israẹli kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti wí, +n óo fi irun aguntan lélẹ̀ ní ibi ìpakà, bí ìrì bà sẹ̀ sórí irun yìí nìkan, tí gbogbo ilẹ̀ tí ó yí i ká bá gbẹ, nígbà náà ni n óo gbà pé nítòótọ́, èmi ni o fẹ́ lò láti gba Israẹli kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti wí.” +Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó jí ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, tí ó sì fún irun aguntan náà, ìrì tí ó fún ní ara rẹ̀ kún abọ́ kan. +Gideoni tún wí fún Ọlọrun pé, “Jọ̀wọ́, má jẹ́ kí inú bí ọ sí mi, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo yìí ni ó kù tí mo fẹ́ sọ̀rọ̀; jọ̀wọ́ jẹ́ kí n tún dán kinní kan wò pẹlu irun aguntan yìí lẹ́ẹ̀kan sí i, jẹ́ kí gbogbo irun yìí gbẹ ṣugbọn kí ìrì sẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀, kí ó sì tutù.” +Wọn a gbógun tì wọ́n, wọn a sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ náà jẹ́ títí dé agbègbè Gasa. Wọn kì í fi oúnjẹ kankan sílẹ̀ rárá ní ilẹ̀ Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fi aguntan tabi mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan sílẹ̀. +Ọlọrun tún ṣe bẹ́ẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà, nítorí pé, orí irun yìí nìkan ṣoṣo ni ó gbẹ, ìrì sì sẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀. +Nítorí pé, nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀, tilé-tilé ni wọ́n wá. Wọn á kó àwọn àgọ́ wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ́wọ́, wọn á sì bo àwọn ọmọ Israẹli bí eṣú. Àwọn ati ràkúnmí wọn kò níye, nítorí náà nígbà tí wọ́n bá dé, wọn á jẹ gbogbo ilẹ̀ náà ní àjẹrun. +Àwọn ọmọ Israẹli di ẹni ilẹ̀ patapata, nítorí àwọn ará Midiani. Nítorí náà, wọ́n ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. +Nígbà tí wọ́n ké pe OLUWA, nítorí ìyọnu àwọn ará Midiani, +OLUWA rán wolii kan sí wọn. Wolii náà bá sọ fún wọn pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Mo ko yín wá láti ilẹ̀ Ijipti, mo ko yín kúrò ní oko ẹrú. +Mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati gbogbo àwọn tí wọn ń ni yín lára. Mo lé wọn jáde fún yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fun yín. +Gideoni Ṣẹgun Àwọn Ará Midiani. +Nígbà tí ó yá, Gideoni, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Jerubaali, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ kan, wọ́n lọ pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ odò Harodu. Àgọ́ ti àwọn ará Midiani wà ní apá ìhà àríwá wọn ní àfonífojì lẹ́bàá òkè More. +Ṣugbọn bí ẹ̀rù bá ń bà ọ láti lọ, mú Pura iranṣẹ rẹ, kí ẹ jọ lọ sí ibi àgọ́ náà. +O óo gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, lẹ́yìn náà, o óo ní agbára láti lè gbógun ti àgọ́ náà.” Gideoni bà mú Pura, iranṣẹ rẹ̀, wọ́n jọ lọ sí ìpẹ̀kun ibi tí àwọn tí wọ́n di ihamọra ogun ninu àgọ́ wọn wà. +Àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati ti Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìlà oòrùn pọ̀ nílẹ̀ lọ bí eṣú àwọn ràkúnmí wọn kò níye, wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun. +Nígbà tí Gideoni dé ibẹ̀, ó gbọ́ tí ẹnìkan ń rọ́ àlá tí ó lá fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan pé, “Mo lá àlá kan, mo rí i tí àkàrà ọkà baali kan ré bọ́ sinu ibùdó àwọn ará Midiani. Bí ó ti bọ́ lu àgọ́ náà, ó wó o lulẹ̀, ó sì dojú rẹ̀ délẹ̀, àgọ́ náà sì tẹ́ sílẹ̀ pẹrẹsẹ.” +Ẹnìkejì rẹ̀ dá a lóhùn, ó ní, “Èyí kì í ṣe ohun mìíràn, bíkòṣe idà Gideoni, ọmọ Joaṣi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli. Ọlọrun ti fi Midiani ati gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ lé e lọ́wọ́.” +Nígbà tí Gideoni gbọ́ bí ó ti rọ́ àlá yìí, ati ìtumọ̀ rẹ̀, ó yin OLUWA. Ó pada sí ibùdó Israẹli, ó ní, “Ẹ dìde, nítorí OLUWA ti fi àwọn ọmọ ogun Midiani le yín lọ́wọ́.” +Ó pín àwọn ọọdunrun (300) náà sí ọ̀nà mẹta, ó fi fèrè ogun ati ìkòkò òfìfo tí wọn fi ògùṣọ̀ sí ninu lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́. +Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe bí mo bá ti ń ṣe. Nígbà tí mo bá dé ìkangun àgọ́ náà, ẹ ṣe bí mo bá ti ṣe. +Nígbà tí èmi ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ mi bá fọn fèrè, ẹ̀yin náà ẹ fọn fèrè tiyín ní gbogbo àyíká àgọ́ náà, ẹ óo sì pariwo pé, ‘Fún OLUWA, ati fún Gideoni.’ ” +Gideoni ati ọgọrun-un eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá lọ sí ìkangun àgọ́ náà ní òru, nígbà tí àwọn olùṣọ́ mìíràn ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ipò àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀. Wọ́n fọn fèrè, wọ́n sì fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà lọ́wó�� wọn mọ́lẹ̀. +OLUWA wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pọ̀jù fún mi, láti fi àwọn ará ilẹ̀ Midiani lé lọ́wọ́, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà gbéraga pé agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun, wọn kò sì ní fi ògo fún mi. +Àwọn ẹgbẹ́ mẹtẹẹta fọn fèrè wọn, wọ́n sì fọ́ ìkòkò tì ó wà lọ́wọ́ wọn. Wọ́n fi iná ògùṣọ̀ wọn sí ọwọ́ òsì, wọ́n sì fi fèrè tí wọn ń fọn sí ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n bá pariwo pé, “Idà kan fún OLUWA ati fún Gideoni.” +Olukuluku wọn dúró sí ààyè wọn yípo àgọ́ náà, gbogbo àwọn ọmọ ogun Midiani bá bẹ̀rẹ̀ sí sá káàkiri, wọ́n ń kígbe, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. +Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Gideoni fọn ọọdunrun (300) fèrè wọn, Ọlọrun mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá wọn dojú ìjà kọ ara wọn, gbogbo wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí apá Serera. Wọ́n sá títí dé Beti Ṣita, ati títí dé ààlà Abeli Mehola, lẹ́bàá Tabati. +Àwọn ọmọ ogun Israẹli pe àwọn ọkunrin Israẹli jáde láti inú ẹ̀yà Nafutali, ati ti Aṣeri ati ti Manase, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ará Midiani lọ. +Gideoni rán àwọn oníṣẹ́ jákèjádò agbègbè olókè Efuraimu, ó ní, “Ẹ máa bọ̀ wá bá àwọn ará Midiani jagun, kí ẹ sì gba ojú odò lọ́wọ́ wọn títí dé Bẹtibara ati odò Jọdani.” Wọ́n pe gbogbo àwọn ọkunrin Efuraimu jáde, wọ́n sì gba gbogbo odò títí dé Bẹtibara ati odò Jọdani pẹlu. +Wọ́n mú Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji, wọ́n pa Orebu sí ibi òkúta Orebu, wọ́n sì pa Seebu níbi ìfúntí Seebu, bí wọ́n ti ń lé àwọn ará Midiani lọ. Wọ́n gé orí Orebu ati ti Seebu, wọ́n sì gbé wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gideoni ní òdìkejì odò Jọdani. +Nítorí náà, kéde fún gbogbo wọn pé, kí ẹnikẹ́ni tí ẹ̀rù bá ń bà pada sí ilé.” Gideoni bá dán wọn wò lóòótọ́, ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) ọkunrin ninu wọn sì pada sí ilé. Àwọn tí wọ́n kù jẹ́ ẹgbaarun (10,000). +OLUWA tún wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù yìí pọ̀jù sibẹsibẹ. Kó wọn lọ sí etí odò, n óo sì bá ọ dán wọn wò níbẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí mo bá wí fún ọ pé yóo lọ, òun ni yóo lọ, ẹnikẹ́ni tí mo bá sì wí fún ọ pé kò ní lọ, kò gbọdọ̀ lọ.” +Gideoni bá kó àwọn eniyan náà lọ sí etí odò, OLUWA bá wí fún Gideoni pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ahọ́n lá omi gẹ́gẹ́ bí ajá, yọ ọ́ sọ́tọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan, bákan náà ni kí o ṣe ẹnikẹ́ni tí ó bá kúnlẹ̀ kí ó tó mu omi. +Àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ bomi, tí wọ́n sì fi ahọ́n lá a bí ajá jẹ́ ọọdunrun (300), gbogbo àwọn yòókù ni wọ́n kúnlẹ̀ kí wọ́n tó mu omi. +OLUWA bá wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọọdunrun (300) tí wọ́n fi ahọ́n lá omi ni n óo lò láti gbà yín là, n óo sì fi àwọn ará Midiani lé ọ lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn yòókù pada sí ilé wọn.” +Gideoni bá gba oúnjẹ àwọn eniyan náà ati fèrè ogun wọn lọ́wọ́ wọn, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n pada sí ilé, ṣugbọn ó dá àwọn ọọdunrun (300) náà dúró. Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Midiani wà ní àfonífojì lápá ìsàlẹ̀ ibi tí wọ́n wà. +OLUWA sọ fún un ní òru ọjọ́ kan náà pé, “Gbéra, lọ gbógun ti àgọ́ náà, nítorí pé mo ti fi lé ọ lọ́wọ́. +Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Àwọn Ará Midiani ní Àṣẹ́tán. +Àwọn ará Efuraimu bèèrè lọ́wọ́ Gideoni pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, tí o kò pè wá, nígbà tí o lọ gbógun ti àwọn ara Midiani?” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí i pẹlu ibinu. +Seba ati Salimuna wà ní ìlú Karikori pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn yòókù, gbogbo àwọn ọmọ ogun ìlà oòrùn tí wọ́n ṣẹ́kù kò ju nǹkan bí ẹẹdẹgbaajọ (15,000) lọ, nítorí pé àwọn tí wọ́n ti kú ninu àwọn ọmọ ogun wọn tí wọ́n ń lo idà tó ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000). +Ọ̀nà èrò tí ó wà ní ìlà oòrùn Noba ati Jogibeha ni Gideoni gbà lọ, ó lọ jálu àwọn ọmọ ogun náà láì rò tẹ́lẹ̀. +Seba ati Salimuna bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ, ṣugbọn Gideoni lé àwọn ọba Midiani mejeeji yìí títí tí ó fi mú wọn. Jìnnìjìnnì bá dàbo gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn. +Ọ̀nà àtigun òkè Heresi ni Gideoni gbà nígbà tí ó ń ti ojú ogun pada bọ̀. +Ọwọ́ rẹ̀ tẹ ọdọmọkunrin ará Sukotu kan, ó sì bèèrè orúkọ àwọn olórí ati àwọn àgbààgbà ìlú Sukotu lọ́wọ́ rẹ̀. Ọdọmọkunrin yìí sì kọ orúkọ wọn sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkunrin mẹtadinlọgọrin. +Ó bá wá sọ́dọ̀ àwọn ọkunrin Sukotu, ó ní, “Ẹ wo Seba ati Salimuna, àwọn ẹni tí ẹ tìtorí wọn pẹ̀gàn mi pé ọwọ́ mi kò tíì tẹ̀ wọ́n, tí ẹ kò sì fún àwọn ọmọ ogun mi tí àárẹ̀ mú ní oúnjẹ. Seba ati Salimuna náà nìyí o.” +Ó kó gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú náà, ó sì mú ẹ̀gún ọ̀gàn ati òṣùṣú, ó fi kọ́ wọn lọ́gbọ́n. +Lẹ́yìn náà ó lọ sí Penueli, ó wó ilé ìṣọ́ wọn, ó sì pa àwọn ọkunrin ìlú náà. +Lẹ́yìn náà, ó bi Seba ati Salimuna pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin tí ẹ pa ní Tabori wà?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí o ti rí gan-an ni ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn náà rí, gbogbo wọn dàbí ọmọ ọba.” +Ó dáhùn, ó ní, “Arakunrin mi ni wọ́n, ìyá kan náà ni ó bí wa. Bí OLUWA ti wà láàyè, bí ó bá jẹ́ pé ẹ dá wọn sí ni, ǹ bá dá ẹ̀yin náà sí.” +Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Kí ni mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe? Ohun tí ẹ̀yin ará Efuraimu ṣe, tí ẹ rò pé ohun kékeré ni yìí, ó ju gbogbo ohun tí àwọn ará Abieseri ṣe, tí ẹ kà kún nǹkan bàbàrà lọ. +Ó bá pe Jeteri àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Dìde, kí o sì pa wọ́n,” ṣugbọn ọmọ náà kò fa idà rẹ̀ yọ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á, nítorí ọmọde ni. +Seba ati Salimuna bá dáhùn pé, “Ìwọ alára ni kí o dìde kí o pa wá? Ṣebí bí ọkunrin bá ṣe dàgbà sí ni yóo ṣe lágbára sí.” Gideoni bá dìde, ó pa Seba ati Salimuna, ó sì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn ràkúnmí wọn. +Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Israẹli wí fún Gideoni pé, “Máa jọba lórí wa, ìwọ ati ọmọ rẹ, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ pẹlu, nítorí pé ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Midiani.” +Gideoni dá wọn lóhùn, ó ní “N kò ní jọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ mi kò ní jọba lórí yín, OLUWA ni yóo máa jọba lórí yín.” +Ṣugbọn ó rọ̀ wọ́n pé kí olukuluku wọn fún òun ní yẹtí tí ó wà ninu ìkógun rẹ̀, nítorí pé àwọn ará Midiani a máa lo yẹtí wúrà gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ilẹ̀ Iṣimaeli yòókù. +Wọ́n dá a lóhùn pé, “A óo fi tayọ̀tayọ̀ kó wọn fún ọ.” Wọ́n bá tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀, olukuluku sì bẹ̀rẹ̀ sí ju yẹtí tí ó wà ninu ìkógun rẹ̀ sibẹ. +Gbogbo ìwọ̀n yẹtí wúrà tí ó gbà jẹ́ ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ṣekeli, láìka ohun ọ̀ṣọ́ ati aṣọ olówó iyebíye tí àwọn ọba Midiani wọ̀, ati àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn àwọn ràkúnmí wọn. +Gideoni bá fi wúrà yìí ṣe ère Efodu kan, ó gbé e sí ìlú rẹ̀ ní Ofira, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ ère oriṣa yìí, ó sì di tàkúté fún Gideoni ati ìdílé rẹ̀. +Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ará Midiani, wọn kò sì lè gbérí mọ́; àwọn ọmọ Israẹli sì sinmi ogun jíjà fún ogoji ọdún, nígbà ayé Gideoni. +Gideoni pada sí ilé rẹ̀, ó sì ń gbé ibẹ̀. +Ẹ̀yin ni Ọlọrun fi Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji lé lọ́wọ́. Kí ni ohun tí mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bí ó ṣe dá wọn lóhùn, inú wọ́n yọ́. +Aadọrin ọmọ ni Gideoni bí, nítorí pé ó ní ọpọlọpọ aya. +Obinrin rẹ̀ kan tí ń gbè Ṣekemu náà bí ọmọkunrin kan fún un, orúkọ ọmọ yìí ń jẹ́ Abimeleki. +Gideoni ọmọ Joaṣi ṣaláìsí lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, wọ́n sin ín sinu ibojì Joaṣi, baba rẹ̀, ní Ofira àwọn ọmọ Abieseri. +Bí Gideoni ti ṣaláìsí tán gẹ́rẹ́, àwọn ọmọ Israẹli tún bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa Baali, wọ́n sì sọ Baali-beriti di Ọlọrun wọn. +Wọn kò ranti OLUWA Ọlọrun wọn tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo àyíká wọn. +Wọn kò ṣe ìdílé Gideoni dáradára bí ó ti tọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san gbogbo nǹkan dáradára tí òun náà ti ṣe fún Israẹli. +Gideoni bá lọ sí odò Jọdani, ó sì kọjá odò náà sí òdìkejì rẹ̀, òun ati àwọn ọọdunrun (300) ọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé e. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, sibẹsibẹ wọ́n ń lé àwọn ará Midiani lọ. +Ó bẹ àwọn ará Sukotu, ó ní, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fún àwọn tí wọ́n tẹ̀lé mi ní oúnjẹ, nítorí pé ó ti rẹ̀ wọ́n, ati pé à ń lé Seba ati Salimuna, àwọn ọba Midiani mejeeji lọ ni.” +Àwọn ìjòyè Sukotu dá a lóhùn, wọ́n ní, “Ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Seba ati Salimuna ni, tí a óo fi fún ìwọ ati àwọn ọmọ ogun rẹ ní oúnjẹ?” +Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Kò burú, nígbà tí OLUWA bá fi Seba ati Salimuna lé mi lọ́wọ́, ẹ̀gún ọ̀gàn aṣálẹ̀ ati òṣùṣú ni n óo fi ya ẹran ara yín.” +Ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Penueli, ó sọ ohun kan náà fún wọn, ṣugbọn irú èsì tí àwọn ará Sukotu fún un ni àwọn ará Penueli náà fún un. +Ó sọ fún àwọn ará Penueli pé, “Nígbà tí mo bá pada dé ní alaafia n óo wó ilé ìṣọ́ yìí.” +Abimeleki. +Abimeleki ọmọ Gideoni lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan ìyá rẹ̀ ní Ṣekemu, ó bá àwọn ati gbogbo ìdílé wọn sọ̀rọ̀, ó ní, +Àwọn igi bá lọ sí ọ̀dọ̀ igi ọ̀pọ̀tọ́, wọ́n sọ fún un pé kí ó wá jọba lórí àwọn. +Ṣugbọn igi ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí n pa èso mi dáradára tí ó ládùn tì, kí n wá jọba lórí yín?’ +Àwọn igi bá tún lọ sọ́dọ̀ igi àjàrà, wọ́n wí fún un pé kí ó wá jọba lórí àwọn. +Ṣugbọn igi àjàrà dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí ń pa ọtí mi, tí ń mú inú àwọn oriṣa ati àwọn eniyan dùn tì, kí n wá jọba lórí ẹ̀yin igi?’ +Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn igi sọ fún igi ẹ̀gún pé kí ó wá jọba lórí àwọn. +Igi ẹ̀gún bá dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Tí ó bá jẹ́ pé tinútinú yín ni ẹ fi fẹ́ kí n jọba yín, ẹ wá sábẹ́ ìbòòji mi, n óo sì dáàbò bò yín. Ṣugbọn bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, iná yóo yọ jáde láti ara ẹ̀gún mi, yóo sì jó igi kedari tí ó wà ní Lẹbanoni run.’ +“Ǹjẹ́ òtítọ́ inú ati ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni ẹ fi fi Abimeleki jọba? Ṣé ohun tí ẹ ṣe sí ìdílé Gideoni tọ́? Gbogbo sísìn tí ó sìn yín, ǹjẹ́ irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún un nìyí? +Nítorí pé baba mi fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu nígbà tí ó ń jà fun yín, ó sì gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Midiani. +Ṣugbọn lónìí, ẹ dìde sí ìdílé baba mi, ẹ sì pa aadọrin àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lórí òkúta, ẹ wá fi Abimeleki, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ̀ jọba lórí ìlú Ṣekemu, nítorí pé ó jẹ́ ìbátan yín. +Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé pẹlu òtítọ́ inú, ati ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni ẹ fi ṣe ohun tí ẹ ṣe sí Gideoni ati ìdílé rẹ̀ lónìí, ẹ máa yọ̀ lórí Abimeleki kí òun náà sì máa yọ̀ lórí yín. +kí wọn bèèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu pé, èwo ni wọ́n fẹ́, tí wọ́n sì rò pé ó dára jù fún wọn, kí gbogbo aadọrin ọmọ Gideoni máa jọba lé wọn lórí ni, tabi kí ẹnìkan ṣoṣo jọba lórí wọn? Ó rán wọn létí pé, ìyekan wọn ni òun jẹ́. +Ṣugbọn bí bẹ́ẹ̀ kọ́, iná yóo jáde láti ara Abimeleki, yóo sì run gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu ati Bẹtimilo. Bẹ́ẹ̀ ni iná yóo jáde láti ara àwọn ará ìlú Ṣekemu ati ti Bẹtimilo, yóo sì jó Abimeleki run.” +Jotamu bá sá lọ sí Beeri, ó sì ń gbé ibẹ̀, nítorí ó bẹ̀rù Abimeleki arakunrin rẹ̀. +Abimeleki jọba lórí Israẹli fún ọdún mẹta. +Ọlọrun rán ẹ̀mí burúkú sí ààrin Abimeleki ati àwọn ara ìlú Ṣekemu. Àwọn ará ìlú Ṣekemu sì dìtẹ̀ mọ́ Abimeleki. +Kí ẹ̀san pípa tí Abimeleki pa àwọn aadọrin ọmọ baba rẹ̀ ati ẹ̀jẹ̀ wọn lè wá sórí Abimeleki, ati àwọn ará ìlú Ṣekemu tí wọ́n kì í láyà láti pa wọ́n. +Àwọn ará ìlú Ṣekemu bá rán àwọn kan ninu wọn, wọ́n lọ ba ní ibùba ní orí òkè de Abimeleki. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dá gbogbo àwọn tí wọn ń kọjá lọ́nà; ni ìròyìn bá kan Abimeleki. +Gaali ọmọ Ebedi ati àwọn arakunrin rẹ̀ kó lọ sí Ṣekemu, àwọn ará ìlú Ṣekemu sì gbẹ́kẹ̀lé e. +Àwọn ará ìlú Ṣekemu lọ sinu oko wọn, wọ́n ká èso àjàrà, wọ́n fi pọn ọtí fún wọn. Wọ́n jọ ń ṣe àríyá, wọ́n jọ lọ sí ilé oriṣa wọn, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi Abimeleki ṣe ẹlẹ́yà. +Gaali ọmọ Ebedi bá bèèrè pé, “Ta tilẹ̀ ni Abimeleki? Báwo sì ni àwa ará ìlú Ṣekemu ṣe jẹ́ sí i, tí a fi níláti máa sìn ín? Ṣebí àwọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu, ni Gideoni ati Sebulu, iranṣẹ rẹ̀ máa ń sìn? Kí ló dé tí àwa fi níláti máa sin Abimeleki? +Ìbá ṣe pé ìkáwọ́ mi ni àwọn eniyan yìí wà, ǹ bá yọ Abimeleki kúrò lórí oyè. Ǹ bá sọ fún Abimeleki pé kí ó lọ wá kún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kí ó jáde wá bá mi jà.” +Àwọn eniyan ìyá rẹ̀ bá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní etígbọ̀ọ́ gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu, wọn sì gbà láti tẹ̀lé Abimeleki tayọ̀tayọ̀. Wọ́n ní, “Arakunrin wa ni Abimeleki jẹ́.” +Nígbà tí Sebulu, olórí ìlú náà gbọ́ ohun tí Gaali, ọmọ Ebedi wí, inú bí i gidigidi. +Ó ranṣẹ sí Abimeleki ní Aruma, ó ní, “Gaali, ọmọ Ebedi, ati àwọn arakunrin rẹ̀ ti dé sí Ṣekemu, wọn kò sì ní gbà fún ọ kí o wọ ibí mọ́. +Nítorí náà, tí ó bá di òru, kí ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lọ ba níbùba. +Bí ilẹ̀ bá ti mọ́, tí oòrùn sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ, gbéra, kí o sì gbógun ti ìlú náà. Nígbà tí Gaali ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá sì jáde sí ọ, mú wọn dáradára, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn.” +Abimeleki ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá gbéra ní òru, wọ́n lọ ba níbùba lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ṣekemu, ní ìsọ̀rí mẹrin. +Gaali ọmọ Ebedi bá jáde, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà, Abimeleki ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ sì jáde níbi tí wọ́n ba sí. +Nígbà tí Gaali rí wọn, ó sọ fún Sebulu pé, “Wò ó, àwọn eniyan kan ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti orí òkè.”Sebulu dá a lóhùn pé, “Òjìji òkè ni ò ń wò tí o ṣebí eniyan ni.” +Gaali tún dáhùn, ó ní, “Tún wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti agbede meji ilẹ̀ náà, àwọn kan sì ń bọ̀ láti apá ibi igi Oaku àwọn tíí máa ń wo iṣẹ́.” +Ṣugbọn Sebulu dá a lóhùn, pé, “Gbogbo ẹnu tí ò ń fọ́n pin, tabi kò pin? Ṣebí ìwọ ni o wí pé, ‘Kí ni Abimeleki jẹ́ tí a fi ń sìn ín.’ Àwọn tí ò ń gàn ni wọ́n dé yìí, yára jáde kí o lọ gbógun tì wọ́n.” +Gaali bá kó àwọn ọkunrin Ṣekemu lẹ́yìn, wọ́n lọ gbógun ti Abimeleki. +Wọ́n mú aadọrin owó fadaka ninu ilé oriṣa Baali-beriti fún Abimeleki. Ó fi owó yìí kó àwọn oníjàgídíjàgan ati ìpátá kan jọ wọ́n sì ń tẹ̀lé e kiri. +Abimeleki lé Gaali, Gaali sì sá fún un, ọpọlọpọ eniyan fara gbọgbẹ́ títí dé ẹnu ibodè ìlú. +Abimeleki tún lọ ń gbé Aruma. Sebulu bá lé Gaali ati àwọn arakunrin rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣekemu mọ́. +Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, Abimeleki gbọ́ pé àwọn ará Ṣekemu ń jáde lọ sinu pápá. +Ó kó àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ó pín wọn sí ìsọ̀rí mẹta, wọ́n sì ba níbùba ninu pápá. Bí ó ti rí i pé àwọn eniyan náà ń jáde bọ̀ láti inú ìlú, ó gbógun tì wọ́n, ó sì pa wọ́n. +Abimeleki ati àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sáré, wọ́n lọ gba ẹnu ọ̀nà bodè ìlú. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun meji yòókù sáré sí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu pápá, wọ́n pa wọ́n. +Abimeleki gbógun ti ìlú náà ní gbogbo ọjọ́ náà, ó gbà á, ó sì pa àwọn eniyan inú rẹ̀; ó wó gbogbo ìlú náà palẹ̀, ó sì da iyọ̀ sí i. +Nígbà tí gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilé ìṣọ́ tí ó wà ní Ṣekemu gbọ́, wọ́n sá lọ sí ibi ààbò tí ó wà ní ilé Eli-beriti. +Wọ́n sọ fún Abimeleki pé gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ tí ó wà ní Ṣekemu ti kó ara wọn jọ sí ibìkan. +Abimeleki bá lọ sí òkè Salimoni, òun ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó mú àáké kan lọ́wọ́, ó fi gé ẹrù igi kan jọ, ó gbé e lé èjìká, ó sì sọ fún àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pé, “Ẹ yára ṣe bí ẹ ti rí mi tí mo ṣe.” +Olukuluku wọn náà bá gé ẹrù igi kọ̀ọ̀kan, wọ́n tẹ̀lé Abimeleki. Wọ́n to ẹrù igi wọn jọ sí ara ibi ààbò náà, wọn sọ iná sí i. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ilé ìṣọ́ Ṣekemu sì kú patapata. Wọ́n tó ẹgbẹrun (1,000) eniyan, atọkunrin, atobinrin. +Ó bá lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ofira, ó pa gbogbo aadọrin àwọn arakunrin rẹ̀ lórí òkúta kan, àfi Jotamu àbíkẹ́yìn Gideoni nìkan ni ó ṣẹ́kù, nítorí pé òun sá pamọ́. +Abimeleki tún lọ sí Tebesi, ó gbógun tì í, ó sì gbà á. +Ṣugbọn ilé ìṣọ́ kan tí ó lágbára wà ninu ìlú náà, gbogbo àwọn ará ìlú sá lọ sinu rẹ̀, atọkunrin, atobinrin. Wọ́n ti ara wọn mọ́ inú rẹ̀, wọ́n sì gun òkè ilé ìṣọ́ náà lọ. +Nígbà tí Abimeleki dé ibi ilé ìṣọ́ náà, ó gbógun tì í. Ó súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ìṣọ́ náà láti dáná sun ún. +Obinrin kan bá gbé ọmọ ọlọ kan, ó sọ ọ́ sílẹ̀, ọmọ ọlọ yìí bá Abimeleki lórí, ó sì fọ́ agbárí rẹ̀. +Ó yára pe ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó wí fún un pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o pa mí, kí àwọn eniyan má baà máa wí pé, ‘Obinrin kan ni ó pa á.’ ” Ọdọmọkunrin yìí bá gún un ní idà, ó sì kú. +Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé Abimeleki ti kú, olukuluku gba ilé rẹ̀ lọ. +Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gbẹ̀san lára Abimeleki fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ baba rẹ̀, nítorí pé, ó pa aadọrin àwọn arakunrin rẹ̀. +Ọlọrun sì mú kí gbogbo ìwà ibi àwọn ará Ṣekemu pada sórí wọn. Èpè tí Jotamu ọmọ Gideoni ṣẹ́ sì ṣẹ mọ́ wọn lára. +Gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu ati ti Bẹtimilo bá para pọ̀, wọ́n fi Abimeleki jọba níbi igi Oaku kan tí ó wà níbi ọ̀wọ̀n tí ó wà ní Ṣekemu. +Nígbà tí Jotamu gbọ́, ó gun orí òkè Gerisimu lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ọkunrin Ṣekemu, kí Ọlọrun lè gbọ́ tiyín. +Ní àkókò kan, àwọn igi oko kó ara wọn jọ pé wọ́n fẹ́ ọba, wọ́n lọ sọ́dọ̀ igi Olifi, wọ́n wí fún un pé kí ó máa jọba lórí wọn. +Ṣugbọn igi Olifi dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí n pa òróró ṣíṣe tì, tí àwọn oriṣa ati àwọn eniyan fi ń dá ara wọn lọ́lá tì, kí n má ṣe é mọ́, kí n wá jọba lórí ẹ̀yin igi?’ +Ọlọrun Pe Jeremaya. +Ọ̀rọ̀ Jeremaya, ọmọ Hilikaya, ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí ó wà ní Anatoti, ní ilẹ̀ Bẹnjamini nìyí. +Mo ti fi ọ́ ṣe orí fún àwọn orílẹ̀-èdè ati ìjọba lónìí,láti fà wọ́n tu ati láti bì wọ́n lulẹ̀,láti pa wọ́n run ati láti bì wọ́n ṣubú,láti tún wọn kọ́ ati láti gbé wọn ró.” +OLUWA bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí yìí?”Mo dáhùn, pé, “Ọ̀pá igi Alimọndi ni.” +OLUWA bá wí fún mi pé, “Òtítọ́ ni ohun tí o rí, nítorí mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, n óo sì mú un ṣẹ.” +OLUWA tún bi mí lẹẹkeji, ó ní, “Kí ni o rí?”Mo bá dáhùn pé, “Mo rí ìkòkò kan tí ó ń hó lórí iná, ó tẹ̀ láti ìhà àríwá sí ìhà gúsù.” +OLUWA bá sọ fún mi pé, “Láti ìhà àríwá ni ibi yóo ti dé bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà. +Nítorí pé mò ń pe gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìjọba àríwá, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, àwọn ọba wọn yóo sì tẹ́ ìtẹ́ wọn kalẹ̀ ní ẹnubodè Jerusalẹmu, ati yíká odi gbogbo ìlú Juda. +N óo dá wọn lẹ́jọ́ nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, tí wọn ń sun turari fún àwọn oriṣa, tí wọ́n sì ń bọ ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. +Ṣugbọn, ìwọ dìde, di àmùrè rẹ, kí o sì sọ gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ fún wọn. Má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn ó bà ọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo dẹ́rù bà ọ́ níwájú wọn. +Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ìlú tí a mọ odi yíká lónìí, o di òpó irin ati ògiri tí a fi bàbà mọ fún gbogbo ilẹ̀ yìí, ati fún àwọn ọba ilẹ̀ Juda, àwọn ìjòyè, ati àwọn alufaa rẹ̀, ati àwọn eniyan ilẹ̀ náà. +Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ. Nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́ kalẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Nígbà ayé Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda, ní ọdún kẹtala tí Josaya gun orí oyè ni OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀. +Ó sì tún gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA ní ìgbà ayé Jehoiakimu, ọmọ Josaya, ọba Juda títí di òpin ọdún kọkanla tí Sedekaya ọmọ Josaya jọba ní ilẹ̀ Juda, títí tí ogun fi kó Jerusalẹmu ní oṣù karun-un ọdún náà. +OLUWA sọ fún mi pé, +“Kí n tó dá ọ sinu ìyá rẹ ni mo ti mọ̀ ọ́,kí wọ́n sì tó bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀,mo yàn ọ́ ní wolii fún àwọn orílẹ̀-èdè.” +Mo bá dáhùn pé,“Háà! OLUWA Ọlọrun!Wò ó! N kò mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọde ni mí.” +Ṣugbọn OLUWA dá mi lóhùn, ó ní,“Má pe ara rẹ ní ọmọde,nítorí pé gbogbo ẹni tí mo bá rán ọ sí ni o gbọdọ̀ tọ̀ lọ.Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni o gbọdọ̀ sọ. +Má bẹ̀rù wọn,nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo sì gbà ọ́.” +OLUWA bá na ọwọ́, ó fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé,“Wò ó, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu. +Ìbọ̀rìṣà ati Ìjọ́sìn Tòótọ́. +Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí OLUWA ń ba yín sọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli: +Ṣugbọn OLUWA ni Ọlọrun tòótọ́,òun ni Ọlọrun alààyè, Ọba ayérayé.Tí inú rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ síí ru ayé á mì tìtì,àwọn orílẹ̀-èdè kò lè farada ibinu rẹ̀. +Wí fún wọn pé àwọn ọlọrun tí kì í ṣe àwọn ni wọ́n dá ọ̀run ati ayé yóo parun láyé ati lábẹ́ ọ̀run. +Òun ni ó fi agbára rẹ̀ dá ayé,tí ó fi ọgbọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀,tí ó sì fi òye rẹ̀ ta ojú ọ̀run bí aṣọ. +Bí ó bá fọhùn, omi á máa rọ́kẹ̀kẹ̀ lójú ọ̀run,ó mú kí ìkùukùu gbéra láti òpin ayé,òun ni ó dá mànàmáná fún òjò,tí ó sì mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀. +Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan jẹ́, wọn kò sì ní ìmọ̀;gbogbo àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ni àwọn oriṣa wọn dójútì,nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn ère wọn;kò sí èémí ninu wọn. +Asán ni wọ́n, ohun ìṣìnà sì ni wọ́n;ní àkókò ìjẹníyà wọn, wọn yóo parun ni. +Ìpín Jakọbu kò rí bí àwọn wọnyi,nítorí òun ló dá ohun gbogbo,Israẹli sì ni ẹ̀yà tí ó yàn, gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀;OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. +Ẹ gbé ẹrù yín nílẹ̀,ẹ̀yin tí ọ̀tá dótì wọnyi! +Nítorí OLUWA wí pé,“Mo ṣetán wàyí, tí n óo sọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí nù bí òkò.N óo mú kí ìpọ́njú dé bá wọn,kí wọ́n lè mọ̀ pé nǹkan ṣe àwọn.” +Mo gbé, nítorí mo fara gbọgbẹ́!Ọgbẹ́ náà sì pọ̀.Ṣugbọn mo sọ fún ara mi pé,“Ìyà gan-an ni èyí jẹ́ fún mi,mo sì gbọdọ̀ fara dà á.” +OLUWA ní,“Ẹ má kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ẹ má sì páyà nítorí àwọn àmì ojú ọ̀run,bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tilẹ̀ ń páyà nítorí wọn, +Àgọ́ mi ti wó, gbogbo okùn rẹ̀ sì ti já.Àwọn ọmọ mi ti fi mí sílẹ̀, wọn kò sì sí mọ́.Kò sí ẹni tí yóo máa bá mi pa àgọ́ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóo máa bá mi ta aṣọ àgọ́ mi. +Nítorí pé òmùgọ̀ ni àwọn olùṣọ́-aguntan,wọn kò sì ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA,nítorí náà wọn kò ṣe àṣeyọrí,tí gbogbo agbo wọn sì fi túká. +Ẹ gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ kan! Ó ń tàn kálẹ̀!Ìdàrúdàpọ̀ ńlá ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,tí yóo sọ àwọn ìlú Juda di ahoroyóo sì di ibùgbé àwọn ajáko. +OLUWA, mo mọ̀ pé ọ̀nà ẹ̀dá kò sí ní ọwọ́ ara rẹ̀.Kò sí ní ìkáwọ́ ẹni tí ń rìn láti tọ́ ìṣísẹ̀ ara rẹ̀. +Tọ́ mi sọ́nà, OLUWA,ṣugbọn lọ́nà ẹ̀tọ́ ni kí o bá mi wí,kì í ṣe pẹlu ibinu rẹ,kí o má baà sọ mí di ẹni ilẹ̀. +Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀ ọ́,ni kí o bínú sí kí ó pọ̀,ati àwọn tí wọn kì í jọ́sìn ní orúkọ rẹ;nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run,wọ́n jẹ ẹ́ ní àjẹrun patapata,wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro. +nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn àṣà wọn.Wọn á gé igi ninu igbó,agbẹ́gilére á fi àáké gbẹ́ ẹ. +Wọn á fi fadaka ati wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,wọn á sì fi ìṣó kàn án mọ́lẹ̀,kí ó má baà wó lulẹ̀. +Ère wọn dàbí aṣọ́komásùn ninu oko ẹ̀gúsí,wọn kò lè sọ̀rọ̀,gbígbé ni wọ́n máa ń gbé wọnnítorí pé wọn kò lè dá rìn.Ẹ má bẹ̀rù wọnnítorí pé wọn kò lè ṣe ẹnikẹ́ni ní ibi kankan,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì lè ṣe rere.” +OLUWA, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, o tóbi lọ́ba,agbára orúkọ rẹ sì pọ̀. +Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè? Nítorí ẹ̀tọ́ rẹ ni;kò sì sí ẹni tí ó gbọ́n tó ọláàrin àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè,ati ni gbogbo ìjọba wọn. +Aláìmọ̀kan ati òmùgọ̀ ni gbogbo wọn,ère kò lè kọ́ eniyan lọ́gbọ́n,nítorí igi lásán ni. +Wọ́n kó fadaka pẹlẹbẹ wá láti ìlú Taṣiṣi,ati wúrà láti ìlú Ufasi.Iṣẹ́ ọwọ́ agbẹ́gilére ni wọ́n,ati ti àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà.Aṣọ wọn jẹ́ aláwọ̀ pupaati ti elése àlùkò,iṣẹ́ ọwọ́ àwọn oníṣọ̀nà ni gbogbo wọn. +Jeremaya ati Majẹmu. +OLUWA bá èmi Jeremaya sọ̀rọ̀, +Wọ́n ti pada sí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Wọ́n ti bá àwọn ọlọrun mìíràn lọ, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Juda ti da majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá. +Nítorí náà, OLUWA ní, òun óo mú kí ibi ó dé bá wọn, ibi tí wọn kò ní lè bọ́ ninu rẹ̀. Ó ní bí wọ́n tilẹ̀ ké pe òun, òun kò ní fetí sí tiwọn. +Ó ní àwọn ìlú Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu yóo ké pe àwọn oriṣa tí wọn ń sun turari sí, ṣugbọn àwọn oriṣa kò ní lè gbà wọ́n lọ́jọ́ ìṣòro. +Bí àwọn ìlú ti pọ̀ tó ní ilẹ̀ Juda bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa ibẹ̀ pọ̀ tó. Bákan náà, Jerusalẹmu, bí òpópó ṣe pọ̀ tó ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ náà ni pẹpẹ tí wọ́n fi ń sun turari sí Baali, tí ó jẹ́ ohun ìtìjú, ṣe pọ̀ tó ninu rẹ̀. +“Nítorí náà, má ṣe gbadura fún àwọn eniyan wọnyi. Má sọkún nítorí wọn, má sì bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí n kò ní gbọ́, nígbà tí wọn bá ké pè mí nígbà ìṣòro wọn. +“Ẹ̀tọ́ wo ni olólùfẹ́ mi níláti wà ninu ilé mi lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú rẹ̀? Ṣé ọpọlọpọ ẹ̀jẹ́ ati ẹran tí a fi rúbọ lè mú kí ibi rékọjá rẹ̀? Ṣé ó lè máa yọ̀ nígbà náà? +Nígbà kan rí, OLUWA pè ọ́ ní igi olifi eléwé tútù, tí èso rẹ̀ dára; ṣugbọn pẹlu ìró ìjì ńlá, yóo dáná sun ún, gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ yóo sì jóná. +OLUWA àwọn ọmọ ogun tí ó gbìn ọ́, ti ṣe ìdájọ́ ibi fún ọ, nítorí iṣẹ́ ibi tí ẹ ṣe, ẹ̀yin ilé Israẹli ati ilé Juda; ẹ mú mi bínú nítorí pé ẹ sun turari sí oriṣa Baali.” +OLUWA fi iṣẹ́ ibi wọn hàn mí, ó sì yé mi. +Ṣugbọn mo dàbí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń fà lọ sọ́dọ̀ alápatà. N kò mọ̀ pé nítorí mi ni wọ́n ṣe ń gbèrò ibi, tí wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gé igi náà lulẹ̀ pẹlu èso rẹ̀, kí á gé e kúrò ní ilẹ̀ alààyè, kí á má sì ranti orúkọ rẹ̀ mọ́.” +ó ní, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ majẹmu yìí, kí o sì sọ ọ́ fún àwọn ọmọ Juda, ati àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. +Ṣugbọn onídàájọ́ òdodo ni ọ́, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ẹni tí ó �� dán ọkàn ati èrò eniyan wò, jẹ́ kí n rí i bí o óo ṣe máa gbẹ̀san lára wọn; nítorí pé ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́. +Nítorí náà, OLUWA sọ nípa àwọn ará Anatoti, tí wọn ń wá ẹ̀mí Jeremaya, tí wọn sì ń sọ fún un pé, “O kò gbọdọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ ní orúkọ OLUWA. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ni a óo pa ọ́.” +Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní òun óo jẹ wọ́n níyà; àwọn ọdọmọkunrin wọn yóo kú lójú ogun, ìyàn ni yóo sì pa àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn. +Kò ní sí ẹni tí yóo ṣẹ́kù nítorí pé òun óo mú kí ibi dé bá àwọn ará Anatoti, nígbà tí àkókò bá tó tí òun óo jẹ wọ́n níyà. +Sọ fún wọn pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ majẹmu +tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, gbé! Majẹmu tí mo bá wọn dá ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná bí iná tí alágbẹ̀dẹ fi ń yọ́ irin.’ Mo sọ fún wọn nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa fetí sí ohùn mi, kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Òun ni ẹ óo fi jẹ́ eniyan mi, tí èmi náà óo sì fi jẹ́ Ọlọrun yín. +Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, n óo mú ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ, pé n óo fún wọn ní ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin,’ bí ó ti rí ní òní.”Mo bá dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, OLUWA.” +OLUWA tún sọ fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Juda ati ní àwọn òpópó Jerusalẹmu, pé kí wọn fetí sí ọ̀rọ̀ majẹmu yìí, kí wọ́n sì ṣe bí ó ti wí. +Mo kìlọ̀ fún àwọn baba ńlá yín ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, títí tí ó sì fi di òní, n kò yé kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n fetí sí ohùn èmi OLUWA. +Sibẹsibẹ wọn kò gbọ́; wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, olukuluku ń ṣe ohun tí ó wà ní ọkàn burúkú rẹ̀. Nítorí náà ni mo ṣe mú kí gbogbo ọ̀rọ̀ majẹmu yìí ṣẹ mọ́ wọn lára, bí mo ti pa á láṣẹ fún wọn pé kí wọn ṣe, ṣugbọn tí wọn kò ṣe.” +OLUWA tún wí fún mi pé, “Àwọn ọmọ Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu ń dìtẹ̀. +OLUWA Káàánú Àwọn Eniyan Rẹ̀. +Olódodo ni ọ́, OLUWA,nígbà tí mo bá ń fẹjọ́ sùn ọ́;sibẹ n óo ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ.Kí ló dé tí nǹkan ń dára fún àwọn eniyan burúkú? +Ọpọlọpọ àwọn darandaran ni wọ́n ti ba ọgbà àjàrà mi jẹ́,wọ́n ti tẹ oko mi mọ́lẹ̀,wọ́n sọ oko mi dáradára di aṣálẹ̀. +Wọ́n sọ ọ́ di ahoro,ilẹ̀ pàápàá ń ráhùn sí mi.Wọ́n ti sọ gbogbo ilẹ̀ náà di ahoro,ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún un. +Àwọn apanirun ti dé sí gbogbo àwọn òkè inú pápá,nítorí pé idà Ọlọrun ni ó ń run eniyan, jákèjádò ilẹ̀ náà;ẹnikẹ́ni kò ní alaafia, +Ọkà baali ni wọ́n gbìn, ṣugbọn ẹ̀gún ni wọ́n kórè.Wọ́n ṣe làálàá, ṣugbọn wọn kò jèrè kankan.Ojú yóo tì wọ́n nígbà ìkórè,nítorí ibinu gbígbóná OLUWA.” +Ohun tí OLUWA sọ nípa gbogbo àwọn aládùúgbò burúkú mi nìyí, àwọn tí wọn ń jí bù lára ilẹ̀ tí mo fún Israẹli, àwọn eniyan mi. Ó ní, “N óo kó wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn; n óo sì kó àwọn ọmọ Juda kúrò láàrin wọn. +Lẹ́yìn tí mo bá kó wọn kúrò tán, n óo pada ṣàánú wọn, n óo dá olukuluku pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀. +Nígbà tí ó bá yá, bí wọ́n bá fi tọkàntọkàn kọ́ àṣà àwọn eniyan mi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ mi búra, tí wọn ń wí pé, ‘Bí OLUWA Ọlọrun ti wà láàyè’, bí àwọn náà ṣe kọ́ àwọn eniyan mi láti máa fi orúkọ Baali búra, n óo fi ìdí wọn múlẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi. +Ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣe àìgbọràn, n óo yọ ọ́ kúrò patapata, n óo sì pa á run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +O gbìn wọ́n, wọ́n ta gbòǹgbò;wọ́n dàgbà, wọ́n so èso;orúkọ rẹ kò jìnnà sẹ́nu wọn,ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí ọ. +Ṣugbọn ìwọ OLUWA mọ̀ mí,O rí mi, o sì ti yẹ ọkàn mi wòo mọ èrò mi sí ọ.Fà wọ́n jáde bí aguntan tí wọn ń mú lọ pa,yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìparun. +Yóo ti pẹ́ tó, tí ilẹ̀ náà yóo máa ṣọ̀fọ̀,tí koríko oko yóo rọ?Nítorí iṣẹ́ burúkú àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀,àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ ṣègbé,nítorí àwọn eniyan ń wí pé,“Kò ní rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wa.” +OLUWA ní,“Bí o bá àwọn tí ń fi ẹsẹ̀ sáré sáré, tí ó bá rẹ̀ ọ́,báwo ni o ṣe lè bá ẹṣin sáré?Bí o bá sì ń ṣubú ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú,báwo ni o óo ti ṣe nígbà tí o bá dé aṣálẹ̀ Jọdani? +Nítorí pé àwọn arakunrin rẹ pàápàáati àwọn ará ilé baba rẹti hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí ọ;àwọn gan-an ni wọ́n ń ṣe èké rẹ:Má gbẹ́kẹ̀lé wọn,bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rere sí ọ.” +OLUWA wí pé,“Mo ti kọ ilé mi sílẹ̀;mo ti kọ ogún tí a pín fún mi sílẹ̀.Mo ti fa ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́. +Ogún mi ti dàbí kinniun inú igbó sí mi,ó ti sọ̀rọ̀ burúkú sí mi;nítorí náà mo kórìíra rẹ̀. +Ṣé ogún mi ti dàbí ẹyẹ igún aláwọ̀ adíkálà ni?Ṣé àwọn ẹyẹ igún ṣùrù bò ó ni?Ẹ lọ pe gbogbo àwọn ẹranko igbó jọ,ẹ kó wọn wá jẹun. +Òwe Aṣọ Funfun. +OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ ra aṣọ funfun kan, kí o lọ́ ọ mọ́ ìdí, má sì tì í bọ omi rárá.” +Àwọn ẹni ibi wọnyi, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ tèmi, tí wọn ń fi oríkunkun tẹ̀lé ìfẹ́ ọkàn wọn, tí wọ́n sì ti sá tọ àwọn oriṣa lọ, tí wọn ń sìn wọ́n, tí wọn sì ń bọ wọ́n. Wọn yóo dàbí aṣọ yìí tí kò wúlò fún ohunkohun. +Bí aṣọ ìlọ́dìí tií lẹ̀ mọ́ ọkunrin lára, bẹ́ẹ̀ ni mo mú kí gbogbo ilé Israẹli ati gbogbo ilé Juda súnmọ́ mi, kí wọ́n lè jẹ́ eniyan mi, ati orúkọ mi, ìyìn mi, ati ògo mi. Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.” +OLUWA ní, “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún.’ Wọn yóo dá ọ lóhùn pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún ni?’ +Ìwọ wá wí fún wọn pé, èmi OLUWA ní n óo rọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí ní ọtí àrọyó, ati àwọn ọba tí wọn jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ati àwọn alufaa, àwọn wolii ati gbogbo àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. +N óo máa sọ wọ́n lu ara wọn. Baba ati ọmọ yóo máa kọlu ara wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N kò ní ṣàánú wọn, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yọ́nú sí wọn débi pé kí n má fẹ́ pa wọ́n run.” +Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́,ẹ má gbéraga nítorí pé OLUWA ló sọ̀rọ̀. +Ẹ fi ògo fún OLUWA Ọlọrun yín kí ó tó mú òkùnkùn ṣú.Kí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ kọ lórí òkè,níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀.Nígbà tí ẹ bá ń wá ìmọ́lẹ̀,yóo sọ ọ́ di ìṣúdudu,yóo sọ ọ́ di òkùnkùn biribiri. +Ṣugbọn bí ẹ kò bá ní gbọ́,ọkàn mi yóo sọkún níkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín.N óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,omi yóo sì máa dà lójú mi,nítorí a ti kó agbo OLUWA ní ìgbèkùn. +Wí fún ọba ati ìyá ọba pé,“Ẹ sọ̀kalẹ̀ lórí ìtẹ́ yín,nítorí adé yín tí ó lẹ́wà ti ṣí bọ́ sílẹ̀ lórí yín.” +Wọ́n ti sé ìlẹ̀kùn odi àwọn ìlú ilẹ̀ Nẹgẹbukò sì sí ẹni tí yóo ṣí wọn.A ti kó gbogbo Juda lọ sí ìgbèkùn,gbogbo wọn pátá ni a ti kó lọ. +Mo bá ra aṣọ funfun náà, bí OLUWA ti wí, mo lọ́ ọ mọ́ ìdí. +Ẹ gbé ojú sókè,kí ẹ wo àwọn tí ń bọ̀ láti ìhà àríwá.Àwọn agbo ẹran tí a fun yín dà,àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí ó lẹ́wà àwọn dà? +Kí ni ẹ óo máa wí nígbà tí OLUWA bá mú àwọn tí ẹ fi ṣe ọ̀rẹ́,tí ó fi wọ́n jọba le yín lórí?Ǹjẹ́ ìnira kò ní ba yín, bí ìrora obinrin tí ń rọbí? +Bí ẹ bá wí lọ́kàn yín pé,“Kí ló dé tí irú èyí fi dé bá wa?”Ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó pọ̀, ni a fi ká aṣọ ní ìdí yín,tí a sì jẹ yín níyà. +Ṣé ó ṣeéṣe kí ará Kuṣi yí àwọ̀ ara rẹ̀ pada?Àbí kí àmọ̀tẹ́kùn fọ tóótòòtóó ara rẹ̀ dànù?Bí ó bá ṣeéṣe, á jẹ́ wí pé ẹ̀yin náà lè hùwà rere;ẹ̀yin tí ibi ṣíṣe ti mọ́ lára. +N óo fọn yín ká bí ìyàngbòtí afẹ́fẹ́ láti inú aṣálẹ̀ ń fẹ́ kiri. +Èyí ni ìpín yín,ìpín tí mo ti yàn fun yín,nítorí pé ẹ ti gbàgbé èmi OLUWA, ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ọlọrun èké. +Èmi gan-an ni n óo ká aṣọ lára yín,n óo sì fi bò yín lójú, kí ayé lè rí ìhòòhò yín. +Mo ti rí ìwà ìbàjẹ́ yín,gbogbo ìwà àgbèrè yín, bí ẹ tí ń yan ká bí akọ ẹṣin,ati ìwà ìṣekúṣe yín ní orí àwọn òkè ninu pápá.Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gbé!Yóo ti pẹ́ tó kí á tó wẹ̀ yín mọ́? +OLUWA tún sọ fún mi lẹẹkeji pé, +“Dìde, mú aṣọ funfun tí o rà, tí o lọ́ mọ́ ìdí, lọ sí odò Yufurate, kí o lọ fi pamọ́ sí ihò àpáta níbẹ̀.” +Mo bá lọ fi pamọ́ sí ẹ̀bá odò Yufurate bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún mi. +Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́, OLUWA sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí odò Yufurate kí o mú aṣọ tí mo ní kí o fi pamọ́ sibẹ wá.” +Mo bá lọ sí ẹ̀bá odò Yufurate; mo gbẹ́ ilẹ̀, mo yọ aṣọ funfun náà jáde kúrò ní ibi tí mo bò ó mọ́. Ó ti bàjẹ́; kò sì wúlò fún ohunkohun mọ́. +OLUWA sọ fún mi pé, +“Bẹ́ẹ̀ gan-an ni n ��o ṣe sọ ògo Juda ati ti Jerusalẹmu di ìbàjẹ́. +Ọ̀gbẹlẹ̀ Ńlá. +Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Jeremaya nípa ọ̀gbẹlẹ̀ nìyí: +OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé,“Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri,wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn;nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA,nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn,yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” +OLUWA sọ fún mi pé, “Má gbadura pé kí àwọn eniyan wọnyi wà ní alaafia. +Wọn ìbáà gbààwẹ̀, n kò ní gbọ́ igbe wọn. Wọn ìbáà rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, n kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Idà, ati ebi, ati àjàkálẹ̀ àrùn, ni n óo fi pa wọ́n run.” +Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, wò ó! Àwọn wolii ń sọ fún wọn pé, wọn kò ní fojú kan ogun, tabi ìyàn, ati pé, alaafia tòótọ́ ni o óo fún wọn ní ibí yìí.” +OLUWA bá sọ fún mi pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ni àwọn wolii ń sọ ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́, n kò fún wọn láṣẹ, n kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí; iṣẹ́ asán ni wọ́n ń wò. Ohun tí ó wà lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ. +Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA sọ ni pé, àwọn wolii tí n kò rán níṣẹ́, tí wọn ń jíṣẹ́ orúkọ mi, tí wọn ní èmi sọ pé ogun ati ìyàn kò ní wọ ilẹ̀ yìí, ogun ati ìyàn ni yóo pa àwọn gan-an run. +Wọn óo gbé àwọn eniyan tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún sọ síta ní òkú ní ìgboro Jerusalẹmu, nígbà tí ìyàn ati ogun bá pa wọ́n tán. Kò ní sí ẹni tí yóo sin òkú wọn, ati ti àwọn iyawo wọn, ati ti àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin. N óo da ibi tí wọ́n ṣe lé wọn lórí.” +OLUWA wí fun mi pé, “Sọ fún wọn pé,‘Kí omijé máa ṣàn lójú mi tọ̀sán-tòru,kí ó má dáwọ́ dúró,nítorí ọgbẹ́ ńlá tí a fi tagbára tagbára ṣá eniyan mi. +Bí mo bá jáde lọ sí ìgbèríko,àwọn tí wọ́n fi idà pa ni wọ́n kún bẹ̀!Bí mo bá sì wọ ààrin ìlú,àwọn tí ìyàn di àìsàn sí lára ni wọ́n kún bẹ̀.Nítorí àwọn wolii ati àwọn alufaa ń lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà,wọn kò sì mọ ohun tí wọn ń ṣe.’ ” +OLUWA, ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ patapata ni?Àbí Sioni ti di ohun ìríra lọ́kàn rẹ?Kí ló dé tí o fi lù wá,tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀rọ̀ tiwa kọjá ìwòsàn?À ń retí alaafia, ṣugbọn ire kankan kò dé.À ń retí àkókò ìwòsàn, ṣugbọn ìpayà ni a rí. +“Juda ń ṣọ̀fọ̀,àwọn ẹnubodè ìlú rẹ̀ wà ninu ìnira.Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń sọkún ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀,igbe àwọn ará Jerusalẹmu sì ta sókè. +OLUWA, a mọ ìwà burúkú wa,ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa,nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́. +Má ta wá nù nítorí orúkọ rẹ,má sì fi àbùkù kan ìtẹ́ rẹ tí ó lógo.Ranti majẹmu tí o bá wa dá,ranti, má sì ṣe dà á. +Ninu gbogbo àwọn ọlọrun èké tí àwọn orílẹ̀-èdè ń sìn,ǹjẹ́ ọ̀kan wà tí ó lè mú kí òjò rọ̀?Àbí ojú ọ̀run ní ń fúnrarẹ̀ rọ ọ̀wààrà òjò?OLUWA Ọlọrun wa, ṣebí ìwọ ni?Ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé,nítorí ìwọ ni o ṣe gbogbo nǹkan wọnyi. +Àwọn ọlọ́lá ní ìlú rán àwọn iranṣẹ wọn lọ pọn omi,àwọn iranṣẹ dé odò, wọn kò rí omi.Wọ́n gbé ìkòkò omi wọn pada lófìfo,ojú tì wọ́n, ìdààmú dé bá wọn,wọ́n káwọ́ lérí. +Nítorí ilẹ̀ tí ó gbẹ,nítorí òjò tí kò rọ̀ ní ilẹ̀ náà,ojú ti àwọn àgbẹ̀, wọ́n káwọ́ lérí. +Àgbọ̀nrín inú igbó pàápàá já ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,nítorí kò sí koríko. +Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè,wọ́n ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ajáko.Ojú wọn rẹ̀wẹ̀sì, nítorí kò sí koríko. +Àwọn eniyan mi ké pè mí wí pé,‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ń jẹ́rìí lòdì sí wa,sibẹsibẹ, nítorí orúkọ rẹ, gbà wá.Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti pada lẹ́yìn rẹ,a ti ṣẹ̀ ọ́. +Ìwọ ìrètí Israẹli,olùgbàlà rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro.Kí ló dé tí o óo fi dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà?Àní, bí èrò ọ̀nà, tí ó yà láti sùn mọ́jú? +Kí ló dé tí o fi dàbí ẹni tí ìdààmú bá;bí alágbára tí kò lè gbani là?Bẹ́ẹ̀ ni o wà láàrin wa, OLUWA,a sì ń fi orúkọ rẹ pè wá,má fi wá sílẹ̀.’ ” +Ìparun Yóo Dé Bá Àwọn Ọmọ Juda. +OLUWA bá tún sọ fún mi pé, “Mose ati Samuẹli ìbáà wá dúró níwájú mi, ọkàn mi kò lè yọ́ sí àwọn eniyan wọnyi. Lé wọn kúrò níwájú mi, kí wọ́n máa lọ! +Mo gbé! Ìyá mi, kí ló dé tí o bí mi, èmi tí mo di oníjà ati alárìíyànjiyàn láàrin gbogbo ìlú! N kò yá ẹnikẹ́ni lówó, bẹ́ẹ̀ n kò yáwó lọ́wọ́ ẹnìkan, sibẹsibẹ gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣépè lé mi. +Kí èpè wọn mọ́ mi, OLUWA, bí n kò b�� sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere níwájú rẹ, bí n kò bá gbadura fún àwọn ọ̀tá mi ní àkókò ìyọnu ati ìdààmú wọn. +Ǹjẹ́ ẹnìkan lè ṣẹ́ irin, pàápàá, irin ilẹ̀ àríwá tí wọn fi idẹ lú? +OLUWA bá dáhùn pé, “Nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, n óo fi ọrọ̀ ati ohun ìṣúra rẹ fún àwọn tí ń kó ìkógun ní gbogbo agbègbè rẹ, láìgba owó lọ́wọ́ wọn. +N óo mú kí o sin àwọn ọ̀tá rẹ ní ilẹ̀ tí o kò dé rí. Mo ti fi ibinu dá iná kan, ó ti ràn, yóo máa jó ọ, kò sì ní kú laelae.” +Mo bá dáhùn pé, “OLUWA, ṣebí ìwọ náà mọ̀? Ranti mi, kí o sì ràn mí lọ́wọ́. Gbẹ̀san mi lára àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni sí mi. Má mú mi kúrò nítorí ojú àánú rẹ. Ranti pé nítorí rẹ ni wọ́n ṣé ń fi mí ṣẹ̀sín. +Nígbà tí mo rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo fi ṣe oúnjẹ jẹ. Nǹkan ayọ̀ ni ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fún mi, ó sì jẹ́ ìdùnnú ọkàn mi. Nítorí orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun. +N kò jókòó láàrin àwọn alárìíyá, bẹ́ẹ̀ ni n kò yọ̀. Mo dá jókòó nítorí àṣẹ rẹ, nítorí o ti fi ìrúnú kún ọkàn mi. +Kí ló dé tí ìrora mi kò dáwọ́ dúró, tí ọgbẹ́ mi jinlẹ̀, tí ó kọ̀, tí kò san? Ṣé o fẹ́ dá mi lọ́kàn le lásán ni; bí ẹlẹ́tàn odò tíí gbẹ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn?” +Nítorí náà OLUWA ní, “Bí o bá yipada, n óo mú ọ pada sípò rẹ, o óo sì tún máa ṣe iranṣẹ mi. Bí o bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ gidi, tí o dákẹ́ ìsọkúsọ, o óo tún pada di òjíṣẹ́ mi. Àwọn ni yóo pada tọ̀ ọ́ wá, o kò ní tọ̀ wọ́n lọ. +Bí wọ́n bá bi ọ́ pé níbo ni kí àwọn ó lọ, sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní, ‘Àwọn tí wọn yóo kú ikú àjàkálẹ̀ àrùn,kì àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n;àwọn tí wọn yóo kú ikú ogun,kí ogun pa wọ́n.Àwọn tí wọn yóo kú ikú ìyàn,kí ìyàn pa wọ́n;àwọn tí wọn yóo lọ sí ìgbèkùn,kí ogun kó wọn lọ.’ +N óo sọ ọ́ di odi alágbára tí a fi idẹ mọ, lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi. Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ, nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́, ati láti yọ ọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, n óo sì rà ọ́ pada lọ́wọ́ àwọn ìkà, aláìláàánú eniyan.” +Oríṣìí ìparun mẹrin ni n óo jẹ́ kí ó dé bá wọn: idà óo pa wọ́n, ajá óo fà wọ́n ya, àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko óo jẹ wọ́n ní àjẹrun. +N óo sọ wọ́n di ohun tí ó bani lẹ́rù fún gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé, nítorí ohun tí Manase, ọmọ Hesekaya, ọba Juda, ṣe ní Jerusalẹmu.” +OLUWA ní,“Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ta ni yóo ṣàánú yín?Ta ni yóo dárò yín?Ta ni yóo ya ọ̀dọ̀ yín, láti bèèrè alaafia yín? +Ẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀,ẹ sì ń pada lẹ́yìn mi; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Nítorí náà ni mo ṣe na ọwọ́ ibinu mi si yín,tí mo sì pa yín run.Mo ti mú sùúrù, ó ti sú mi. +Mo ti fẹ́ wọn bí ẹni fẹ́ ọkà ní ibi ìpakà,ní ẹnubodè ilẹ̀ náà.Mo ti kó ọ̀fọ̀ bá wọn;mo ti pa àwọn eniyan mi run,nítorí wọn kò yipada kúrò ní ọ̀nà wọn. +Mo ti mú kí opó pọ̀ láàrin wọn ju iyanrìn inú òkun lọ.Mo mú kí apanirun gbógun ti àwọn ìyá àwọn ọdọmọkunrin ní ọ̀sán gangan.Mo mú kí ìbẹ̀rù ati ìwárìrì já lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀. +Ẹni tí ó bí ọmọ meje ṣe àárẹ̀, ó sì dákú,oòrùn rẹ̀ wọ̀ lọ́sàn-án gangan.Ìtìjú ati àbùkù bá a.N óo jẹ́ kí ọ̀tá fi idà pa àwọn tí wọ́n kù ninu wọn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Ìfẹ́ OLUWA ní Ìgbésí Ayé Jeremaya. +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +“Bí o bá sọ ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn eniyan náà tán, bí wọn bá bi ọ́ pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi sọ gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú yìí nípa wa? Kí ni a ṣe? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni a ṣẹ OLUWA Ọlọrun wa?’ +Kí o dá wọn lóhùn pé, nítorí pé àwọn baba wọn ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé àwọn ọlọrun mìíràn, wọ́n ń sìn wọ́n, wọ́n sì ń bọ wọ́n. +Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọn kò sì pa òfin mi mọ́. Ẹ̀yin gan-an ti ṣe ohun tí ó burú ju ti àwọn baba yín lọ, ẹ wò bí olukuluku yín tí ń tẹ̀lé agídí ọkàn rẹ̀, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi. +Nítorí náà, n óo gba yín dànù kúrò ní ilẹ̀ yìí; n óo fọn yín dànù bí òkò, sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí. Níbẹ̀ ni ẹ óo ti máa sin oriṣa, tí ẹ óo máa bọ wọ́n tọ̀sán-tòru, nítorí pé n kò ní ṣàánú yín.” +Nítorí náà, OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀, tí wọn kò ní máa búra mọ́ pé, ‘Bí OLUWA, tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti tí ń bẹ,’ +ṣugbọn wọn yóo máa búra pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ, ẹni tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde láti ilẹ̀ àríwá ati láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó lé wọn lọ.’ N óo mú wọn pada sórí ilẹ̀ wọn, ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba wọn.” +Ó ní, “Wò ó, n óo ranṣẹ pe ọpọlọpọ apẹja, wọn yóo sì wá kó àwọn eniyan wọnyi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, n óo ranṣẹ sí ọpọlọpọ ọdẹ, wọn yóo sì wá dọdẹ wọn ní orí gbogbo òkè gíga ati àwọn òkè kéékèèké, ati ninu pàlàpálá àpáta. +Nítorí pé mò ń wo gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, kò sí èyí tí n kò rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò sápamọ́ fún mi. +N óo gbẹ̀san àìdára wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní ìlọ́po meji, nítorí wọ́n ti fi ohun ìríra wọn sọ ilẹ̀ mi di eléèérí. Wọ́n sì ti kó oriṣa ìríra wọn kún ilẹ̀ mi.” +OLUWA, ìwọ ni agbára mi, ati ibi ààbò mi,ìwọ ni ibi ìsápamọ́sí mi, ní ìgbà ìpọ́njú.Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sọ́dọ̀ rẹ,láti gbogbo òpin ayé,wọn yóo máa wí pé:“Irọ́ patapata ni àwọn baba wa jogún,ère lásánlàsàn tí kò ní èrè kankan. +“O kò gbọdọ̀ fẹ́ iyawo tabi kí o bímọ ní ibí yìí. +Ṣé eniyan lè fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣẹ̀dá ọlọrun?Irú ọlọrun bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ọlọrun rárá.” +OLUWA ní, “Nítorí náà, wò ó, n óo jẹ́ kí wọn mọ̀;àní sẹ́, n óo jẹ́ kí wọ́n mọ agbára ati ipá mi;wọn yóo sì mọ̀ pé orúkọ mi ni OLUWA.” +Nítorí ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin tí a bí ní ibí yìí, ati nípa ìyá tí ó bí wọn, ati baba tí a bí wọn fún ni pé, +àìsàn burúkú ni yóo pa wọ́n. Ẹnìkan kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin wọ́n; bí ìgbọ̀nsẹ̀ ni wọn yóo rí lórí ilẹ̀. Ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n run, òkú wọn yóo sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko. +“Má wọ ilé tí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀, má lọ máa kọrin arò, tabi kí o bá wọn kẹ́dùn, nítorí mo ti mú alaafia mi ati ìfẹ́ mi ati àánú mi kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi. +Àtàwọn eniyan pataki pataki, ati mẹ̀kúnnù, ni yóo kú ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní rí ẹni sin òkú wọn, kò ní sí ẹni tí yóo sọkún wọn; ẹnìkan kò ní fi abẹ ya ara, tabi kí ẹnìkan fá orí nítorí wọn. +Kò ní sí ẹni tí yóo fún ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní oúnjẹ láti tù ú ninu, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò sì ní bu omi fún ẹnìkan mu, nítorí ikú baba tabi ìyá rẹ̀. +“O kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí wọ́n ti ń se àsè, má bá wọn jókòó láti jẹ tabi láti mu. +Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: ‘Wò ó! N óo fi òpin sí ẹ̀rín ati ìró ayọ̀ ní ibí yìí, n óo sì fi òpin sí ohùn iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé ati ti ọkọ iyawo. Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ níṣojú yín, ní ìgbà ayé yín.’ +Ẹ̀ṣẹ̀ ati Ìjìyà Juda. +OLUWA ní, “Gègé irin ni a fi kọ ẹ̀ṣẹ̀ Juda sílẹ̀ gègé òkúta dayamọndi ni a sì fi kọ ọ́ sí ọkàn yín, ati sí ara ìwo ara pẹpẹ wọn, +Èmi OLUWA ni èmi máa ń wádìí èrò eniyan, tí èmi sì máa ń yẹ ọkàn eniyan wò,láti san án fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀,ati gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Bí àparò tíí pa ẹyin ẹlẹ́yinbẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó fi èrú kó ọrọ̀ jọ.Ọrọ̀ yóo lọ mọ́ ọn lọ́wọ́ lọ́sàn-án gangan,nígbẹ̀yìn yóo di òmùgọ̀. +Ìtẹ́ ògo tí a tẹ́ sí ibi gíga láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ibi mímọ́ wa. +OLUWA, ìwọ ni Israẹli gbójú lé,ojú yóo ti gbogbo àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀.A óo kọ orúkọ àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ sórí ilẹ̀,yóo sì parẹ́,nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA, orísun omi ìyè, sílẹ̀. +Wò mí sàn, OLUWA, ara mi yóo sì dá,gbà mí, n óo sì bọ́ ninu ewu.Nítorí pé ìwọ ni mò ń yìn. +Wò ó! Wọ́n ń bi mí pé,“Níbo ni gbogbo ìhàlẹ̀ OLUWA já sí?Jẹ́ kí ó ṣẹ, kí á rí i!” +N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o rán ibi sí wọn,bẹ́ẹ̀ ni n kò fẹ́ ọjọ́ ibi fún wọn.OLUWA, o mọ̀ bẹ́ẹ̀.Ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde kò tún lè ṣàjèjì sí ọ. +Má di ohun ẹ̀rù fún mi,nítorí ìwọ ni ibi ààbò mi ní ọjọ́ ibi. +Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni mi,ṣugbọn kí ojú má tì mí.Jẹ́ kí ìpayà bá wọn,ṣugbọn má jẹ́ kí èmi páyà.Mú ọjọ́ ibi dé bá wọn; pa wọ́n run ní àpatúnpa. +OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ dúró ní ẹnubodè Bẹnjamini níbí, tí àwọn ọba Juda máa ń gbà wọlé, tí wọn sìí gbà jáde; ati ní gbogbo ẹnubodè Jerusalẹmu, +níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá ń ranti àwọn pẹpẹ yín, ati àwọn oriṣa Aṣera yín, tí ẹ rì mọ́ ẹ̀gbẹ́ gbogbo igi tútù, ati lórí àwọn òkè gíga; +kí o wí pé, ‘Ẹ gbọ́ bí OLUWA ti wí, ẹ̀yin ọba Juda, ati gbogbo ẹ̀yin ará Juda ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gba ẹnu ọ̀nà wọnyi wọlé. +OLUWA ní kí ẹ ṣọ́ra fún ẹ̀mí yín, ẹ má máa ru ẹrù ní ọjọ́ ìsinmi, ẹ má gbé ẹrù wọ ẹnubodè Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi mọ́. +Ẹ kò gbọdọ̀ ru ẹrù jáde ní ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, ẹ níláti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, bí mo ti pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín. +Sibẹ àwọn baba yín kò gbọ́; wọn kò sì fetí sílẹ̀, wọ́n ṣe oríkunkun, kí wọn má baà gbọ́, kí wọn má baà gba ìtọ́ni. +Ṣugbọn bí ẹ̀yin bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò gbé ẹrù wọ inú ìlú yìí lọ́jọ́ ìsinmi, tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́ láìṣe iṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà, +àwọn ọba tí yóo máa gúnwà lórí ìtẹ́ Dafidi, yóo máa gba ẹnubodè ìlú yìí wọlé. Àwọn ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn ará Juda ati ará ìlú Jerusalẹmu yóo máa gun ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun wọlé. Àwọn eniyan yóo sì máa gbé ìlú yìí títí ayé. +Àwọn eniyan yóo máa wá láti gbogbo ìlú Juda ati àwọn agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Bẹnjamini ati pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela, láti àwọn agbègbè olókè ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, wọn yóo máa mú ẹbọ sísun ati ẹbọ ọrẹ wá, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati turari; wọn yóo máa mú ẹbọ ọpẹ́ wá sí ilé OLUWA. +Ṣugbọn bí ẹ kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, tí ẹ̀ ń ru ẹrù wọ inú Jerusalẹmu lọ́jọ́ ìsinmi, n óo ṣá iná sí ẹnubodè Jerusalẹmu, yóo jó àwọn ààfin rẹ̀, kò sì ní ṣe é pa.’ ” +ati lórí àwọn òkè ninu pápá. N óo sọ gbogbo ọrọ̀ yín ati gbogbo ohun ìṣúra yín di ìkógun fún àwọn ọ̀tá yín; n óo fi gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ yín ní gbogbo ilẹ̀ yín. +Ìwà yín yóo mú kí ilẹ̀ tí mo fun yín bọ́ lọ́wọ́ yín; n óo sí sọ yín di ẹrú àwọn ọ̀tá yín ní ilẹ̀ tí ẹ kò mọ̀rí. Ẹ ti mú kí ibinu mi máa jó bí iná, kò sì ní kú títí lae.” +OLUWA ní,“Ègún ni fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé eniyan,tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe agbára rẹ̀;tí ọkàn rẹ̀ yipada kúrò lọ́dọ̀ èmi OLUWA. +Ó dàbí igbó ṣúúrú ninu aṣálẹ̀,nǹkan rere kan kò lè ṣẹlẹ̀ sí i.Ninu ilẹ̀ gbígbẹ, ninu aṣálẹ̀ ni ó wà,ninu ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé. +“Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,tí ó fi OLUWA ṣe àgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀. +Yóo dàbí igi tí a gbìn sí ipa odò, tí ó ta gbòǹgbò kan ẹ̀bá odò.Ẹ̀rù kò ní bà á nígbà tí ẹ̀ẹ̀rùn bá dé,nítorí pé ewé rẹ̀ yóo máa tutù minimini.Kò ní páyà lákòókò ọ̀gbẹlẹ̀,nígbà gbogbo ni yóo sì máa so. +“Ọkàn eniyan kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ,ìwà ìbàjẹ́ sì kún inú rẹ̀;ta ni ó lè mọ èrò ọkàn eniyan? +Jeremaya nílé Amọ̀kòkò. +OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀, ó ní: +bí ó bá ṣe nǹkan burúkú lójú mi, tí kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, n óo dá nǹkan rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún un dúró. +Nítorí náà, sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, èmi OLUWA ní, mò ń pète ibi kan si yín, mo sì ń pinnu rẹ̀ lọ́wọ́ báyìí, kí olukuluku yín yipada kúrò ninu ibi tí ó ń ṣe; kí ẹ sì tún ìwà ati ìṣe yín ṣe. +Ṣugbọn wọ́n ń wí pé, ‘Rárá o, OLUWA kàn ń sọ tirẹ̀ ni, tinú wa ni a óo ṣe, olukuluku yóo máa lo agídí ọkàn rẹ̀.’ ” +Nítorí náà OLUWA ní,“Ẹ bèèrè láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè,bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ irú rẹ̀ rí.Israẹli ti ṣe ohun tó burú gan-an. +Ṣé yìnyín òkè Lẹbanoni a máa dà ní pàlàpálá Sirioni? Àbí omi tútù tí máa ń ṣàn láti inú òkè rẹ̀ a máa gbẹ? +Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti gbàgbé mi,wọ́n ń sun turari sí oriṣa èké.Wọ́n ti kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà àtijọ́ tí wọn ń tọ̀,wọ́n ti yà sí ọ̀nà ojúgbó tí kì í ṣe ojú ọ̀nà tààrà. +Wọ́n sọ ilẹ̀ wọn di ohun ẹ̀rù ati ohun àrípòṣé títí lae.Gbogbo àwọn tí wọn bá gba ibẹ̀ kọjá ni ẹ̀rù yóo máa bà,tí wọn yóo sì máa mi orí. +N óo fọ́n wọn ká níwájú ọ̀tá bí ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn.Ẹ̀yìn ni n óo kọ sí wọn lọ́jọ́ àjálù,wọn kò ní rí ojú mi.” +Wọ́n bá dáhùn pé, “Ẹ wá, kí á gbìmọ̀ ibi sí Jeremaya, nítorí pé òfin kò ní parun lọ́dọ̀ àwọn alufaa, ìmọ̀ràn kò ní tán lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò sì ní ṣàì máa wà lẹ́nu àwọn wolii. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa pa á, ẹ má sì jẹ́ kí á fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kankan.” +Mo bá gbadura pe,“Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA,kí o sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi. +“Dìde, lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni óo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ.” +Ṣé ibi ni eniyan fi í san rere?Sibẹ wọ́n ti wa kòtò sílẹ̀ fún mi.Ranti bí mo ti dúró níwájú rẹ tí mo sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere,kí o baà lè yí ibinu rẹ pada lórí wọn. +Nítorí náà ìyàn ni kí ó pa àwọn ọmọ wọn,kí ogun pa wọ́n,kí àwọn aya wọn di aláìlọ́mọ ati opó,kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ọmọkunrin wọn,kí idà ọ̀tá sì pa àwọn ọ̀dọ̀ wọn lójú ogun. +Kí igbe ẹkún ó sọ ninu ilé wọn,nígbà tí o bá mú àwọn apanirun wá sórí wọn lójijì;nítorí pé wọ́n wa kòtò láti mú mi,wọ́n dẹ tàkúté sílẹ̀ fún mi. +OLUWA, gbogbo àbá tí wọn ń dá ni o mọ̀,o mọ gbogbo ète tí wọn ń pa láti pa mí.Má dárí ìwà ibi wọn jì wọ́n,má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ níwájú rẹ.Jẹ́ kí wọn ṣubú níwájú rẹ,nígbà tí inú bá ń bí ọ ni kí o bá wọn wí.” +Mo bá lọ sí ilé amọ̀kòkò. Mo bá a tí ó ń mọ ìkòkò kan lórí òkúta tí wọn fi ń mọ ìkòkò. +Ìkòkò tí ó ń fi amọ̀ mọ bàjẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó bá fi amọ̀ náà mọ ìkòkò mìíràn, tí ó wù ú. +OLUWA bá sọ fún mi pé, +“Ẹ̀yin ilé Israẹli, ṣé n kò lè ṣe yín bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ìkòkò tí ó mọ ni? Bí amọ̀ ti rí lọ́wọ́ amọ̀kòkò ni ẹ rí lọ́wọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli. +Bí mo bá sọ pé n óo fa orílẹ̀-èdè kan, tabi ìjọba kan tu, n óo wó o lulẹ̀, n óo sì pa á run, +bí orílẹ̀-èdè ọ̀hún bá yipada kúrò ninu ìwà burúkú rẹ̀, n óo dá ibi tí mo ti fẹ́ ṣe sí i tẹ́lẹ̀ dúró. +Bí mo bá sọ pé n óo gbé orílẹ̀-èdè kan dìde, n óo sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀; +Ìgò Amọ̀ Tí Ó Fọ́. +OLUWA ní kí n lọ ra ìgò amọ̀ kan, kí n mú díẹ̀ ninu àwọn àgbààgbà ìlú ati àwọn bíi mélòó kan ninu àwọn àgbà alufaa, +OLUWA ní lẹ́yìn náà kí n fọ́ ìgò amọ̀ náà ní ojú àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi, +kí n sì sọ fún wọn pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Bí ẹni fọ́ ìkòkò amọ̀ ni n óo ṣe fọ́ àwọn eniyan yìí ati ìlú yìí, kò sì ní ní àtúnṣe mọ́. Ní Tofeti ni wọn yóo máa sin òkú sí nígbà tí wọn kò bá rí ààyè sin òkú sí mọ́. +Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ìlú yìí ati àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀. Bíi Tofeti ni n óo ṣe ìlú náà; Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Àwọn ilé Jerusalẹmu ati àwọn ààfin ọba Juda, gbogbo ilé tí wọn ń sun turari sí àwọn ogun ọ̀run lórí òrùlé wọn, tí wọn sì ti rú ẹbọ ohun mímu sí àwọn oriṣa mìíràn, gbogbo wọn ni yóo di aláìmọ́ bíi Tofeti.” +Nígbà tí Jeremaya pada dé láti Tofeti, níbi tí OLUWA rán an lọ pé kí ó lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀, ó dúró ní àgbàlá ilé OLUWA, ó sọ fún gbogbo àwọn tí wọ́n péjọ sibẹ pé, +“OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘N óo mú kí ibi tí mo ti kéde rẹ̀ dé bá ìlú yìí ati àwọn ìlú tí wọn yí i ká, nítorí wọ́n ti ṣe oríkunkun, wọn kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.’ ” +kí n lọ sí ìsàlẹ̀ àfonífojì ọmọ Hinomu, lẹ́nu Ibodè Àpáàdì; kí n sì kéde ọ̀rọ̀ tí òun óo sọ fún mi níbẹ̀: +“Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọba Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun óo mú ibi kan wá sórí ilẹ̀ yìí, híhó ni etí gbogbo àwọn tí wọn bá gbọ́ nípa rẹ̀ yóo máa hó. +Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ti sọ ibí di aláìmọ́ pẹlu turari tí wọn ń sun sí àwọn oriṣa tí àwọn, ati àwọn baba wọn, ati àwọn ọba Juda kò mọ̀ rí. Wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ sí gbogbo ibí yìí. +Wọ́n kọ́ pẹpẹ oriṣa Baali, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọkunrin wọn rú ẹbọ sísun sí i. N kò pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa ṣe bẹ́ẹ̀, n kò fún wọn ní irú ìlànà bẹ́ẹ̀; ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ wá sí mi lọ́kàn. +Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀, tí a kò ní pe ibí yìí ní Tofeti tabi àfonífojì ọmọ Hinomu mọ́. Àfonífojì ìpànìyàn ni a óo máa pè é. +N óo sọ ìmọ̀ àwọn ará Juda ati ti àwọn ará ìlú Jerusalẹmu di òfo, n óo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá wọn ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn fi idà pa wọ́n. N óo sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko. +N óo sì sọ ìlú yìí di ohun ẹ̀rù ati àrípòṣé, ẹ̀rù ìlú náà yóo sì máa ba gbogbo ẹni tí ó bá kọjá níbẹ̀, wọn yóo máa pòṣé nítorí àjálù tí ó dé bá a. +N óo mú kí wọn máa pa ọmọ wọn ọkunrin ati obinrin jẹ. Olukuluku yóo máa pa aládùúgbò rẹ̀ jẹ nítorí ìdààmú tí àwọn ọ̀tá wọn, ati àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn yóo kó bá wọn, nígbà tí ogun bá dótì wọ́n.” +Ìtọ́jú Ọlọrun lórí Israẹli. +OLUWA sọ fún mi pé, +Ó ní, “Ẹ kọjá sí èbúté àwọn ará Kipru kí ẹ wò yíká,tabi kí ẹ ranṣẹ sí Kedari kí ẹ sì ṣe ìwádìí fínnífínní,bóyá irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ rí. +Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kankan tíì pààrọ̀ ọlọrun rẹ̀ rí,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ọlọrun tòótọ́?Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti pààrọ̀ ògo wọn,wọ́n ti fi ohun tí kò ní èrè pààrọ̀ rẹ̀. +Nítorí náà kí ẹ̀rù kí ó bà ọ́, ìwọ ọ̀run,kí o wárìrì, kí gbogbo nǹkan dàrú mọ́ ọ lójú.” +OLUWA wí pé, “Nítorí pé àwọn eniyan mi ṣe nǹkan burúkú meji:wọ́n ti kọ èmi orísun omi ìyè sílẹ̀,wọ́n ṣe kànga fún ara wọn;kànga tí ó ti là, tí kò lè gba omi dúró. +“Ṣé ẹrú ni Israẹli ni,àbí ọmọ ẹrú tí ẹrú bí sinu ilé?Báwo ló ṣe wá di ìjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. +Àwọn kinniun ti bú mọ́ ọn,wọ́n bú ramúramù.Wọ́n sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro.Àwọn ìlú rẹ̀ sì ti tú, wọ́n ti wó palẹ̀,láìsí eniyan tí ń gbé inú wọn. +Bákan náà, àwọn ará Memfisi ati Tapanhesi ti fọ́ adé orí rẹ̀. +Ṣebí ọwọ́ ara yín ni ẹ fi fà á sí orí ara yín,nígbà tí ẹ̀yin kọ Ọlọrun yín sílẹ̀,nígbà tí ó ń tọ yín sọ́nà? +Kí ni èrè tí ẹ rí nígbà tí ẹ lọ sí Ijipti,tí ẹ lọ mu omi odò Naili,àbí kí ni èrè tí ẹ gbà bọ̀ nígbà tí ẹ lọ sí Asiria,tí ẹ lọ mu omi odò Yufurate. +Ìwà burúkú yín yóo fìyà jẹ yín,ìpadà sẹ́yìn yín yóo sì kọ yín lọ́gbọ́n.Kí ó da yín lójú pé,nǹkan burúkú ni, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kò sì ní dùn,pé ẹ fi èmi OLUWA Ọlọrun yín sílẹ̀;ìbẹ̀rù mi kò sí ninu yín.Èmi, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +“Lọ kéde sí etígbọ̀ọ́ àwọn ará Jerusalẹmu, pé èmi OLUWA ní, mo ranti bí o ti fi ara rẹ jì mí nígbà èwe rẹ, ìfẹ́ rẹ dàbí ìfẹ́ iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé; mo ranti bí o ṣe ń tẹ̀lé mi ninu aṣálẹ̀, ní ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbin nǹkankan sí. +OLUWA wí pé,“Nítorí pé ó ti pẹ́ tí ẹ ti bọ́ àjàgà yín,tí ẹ sì ti tú ìdè yín;tí ẹ sọ pé, ẹ kò ní sìn mí.Ẹ̀ ń lọ káàkiri lórí gbogbo òkè,ati lábẹ́ gbogbo igi tútù;ẹ̀ ń foríbalẹ̀, ẹ̀ ń ṣe bíi panṣaga. +Sibẹ mo gbìn yín gẹ́gẹ́ bí àjàrà tí mo fẹ́,tí èso rẹ̀ dára.Báwo ni ẹ ṣe wá yipada patapata,tí ẹ di àjàrà igbó tí kò wúlò? +Bí ẹ tilẹ̀ fi eérú fọ ara yín,tí ẹ sì fi ọpọlọpọ ọṣẹ wẹ̀,sibẹ, àbààwọ́n ẹ̀bi yín wà níwájú mi. +Báwo ní ẹ ṣe lè wí pé ẹ kì í ṣe aláìmọ́;ati pé ẹ kò tẹ̀lé àwọn oriṣa Baali?Ẹ wo irú ìwà tí ẹ hù ninu àfonífojì,kí ẹ ranti gbogbo ibi tí ẹ ṣebí ọmọ ràkúnmí tí ń lọ, tí ń bọ̀;tí ń tọ ipa ọ̀nà ara rẹ̀. +Ẹ dàbíi Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́, tí aṣálẹ̀ ti mọ́ lára,tí ń ṣí imú kiri,nígbà tí ó ń wa akọ tí yóo gùn ún.Ta ló lè dá a dúró?Kí akọ tí ó bá ń wá amá wulẹ̀ ṣe ara rẹ̀ ní wahala,nítorí yóo yọjú nígbà tí àkókò gígùn rẹ̀ bá tó. +Má rìn láìwọ bàtà, Israẹli,má sì jẹ́ kí òùngbẹ gbẹ ọ́.Ṣugbọn o sọ pé, ‘Kò sí ìrètí,nítorí àjèjì oriṣa ni mo fẹ́,n óo sì wá wọn kiri.’ ” +OLUWA ní, “Bí ojú tíí ti olè nígbà tí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́,bẹ́ẹ̀ ni ojú yóo tì yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.Àtẹ̀yin ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín,ati àwọn alufaa yín, ati àwọn wolii yín; +ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí fún igi pé igi ni baba yín,tí ẹ sì ń sọ fún òkúta pé òkúta ni ó bi yín;nítorí pé dípò kí ẹ kọjú sí ọ̀dọ̀ mi,ẹ̀yìn ni ẹ kọ sí mi.Ṣugbọn nígbà tí ìṣòro dé ba yín,ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pè mí pé kí n dìde, kí n gbà yín là. +“Ṣugbọn níbo ni àwọn oriṣa yín tí ẹ dá fún ara yín wà?Kí wọn dìde, tí wọ́n bá lè gbà yín ní àkókò ìṣòro yín!Ṣebí bí ìlú yín ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa yín náà pọ̀ tó, ẹ̀yin ará Juda. +Ẹjọ́ kí ni ẹ wá ń bá mi rò?Ṣebí gbogbo yín ni ẹ̀ ń bá mi ṣọ̀tẹ̀! +Israẹli jẹ́ mímọ́ fún OLUWAÒun ni àkọ́so èso rẹ̀.Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ ninu àkọ́so èso yìí di ẹlẹ́bi;ibi sì dé bá wọn.Èmi OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.” +Mo na àwọn ọmọ yín lásán ni,wọn kò gba ẹ̀kọ́.Ẹ̀yin gan-an ni ẹ fi idà pa àwọn wolii yín ní àparun,bíi kinniun tí ń pa ẹran kiri. +Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ gbọ́ ohun tí èmi, OLUWA ń sọ.Ṣé aṣálẹ̀ ni mo jẹ́ fún Israẹli;tabi mo ti di ilẹ̀ òkùnkùn biribiri?Kí ló dé tí ẹ̀yin eniyan mi fí ń sọ pé,‘A ti di òmìnira, a lè máa káàkiri;a kò ní wá sí ọ̀dọ̀ rẹ mọ́?’ +Ṣé ọmọbinrin lè gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀?Tabi iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé lè gbàgbé àwọn aṣọ rẹ̀?Sibẹ ẹ ti gbàgbé mi tipẹ́. +“Ẹ mọ oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí eniyan fi í wá olólùfẹ́ kiri,tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ ti fi ìrìnkurìn yínkọ́ àwọn obinrin oníwà burúkú. +Ẹ̀jẹ̀ àwọn talaka tí kò ṣẹ̀, wà létí aṣọ yín;bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bá wọn níbi tí wọ́n ti ń fọ́lé.Gbogbo èyí wà bẹ́ẹ̀, +sibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọwọ́ wa mọ́;dájúdájú, OLUWA ti dá ọwọ́ ibinu rẹ̀ dúró lára wa.’Ẹ wò ó! N óo dá yín lẹ́jọ́,nítorí ẹ̀ ń sọ pé ẹ kò dẹ́ṣẹ̀. +Ẹ̀ ń fi ara yín wọ́lẹ̀ káàkiri;ẹ̀ ń yà síhìn-ín sọ́hùn-ún!Bí Asiria ti dójú tì yín,bẹ́ẹ̀ ni Ijipti náà yóo dójú tì yín. +Ẹ óo ká ọwọ́ lérí ninígbà tí ẹ óo bá jáde níbẹ̀.Nítorí OLUWA ti kọ àwọn tí ẹ gbójúlé,wọn kò sì ní ṣe yín níre.” +Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ilé Jakọbu, ati gbogbo ìdílé Israẹli. +OLUWA ní: “Nǹkan burúkú wo ni àwọn baba ńlá yín ní mo fi ṣe àwọn, tí wọ́n jìnnà sí mi; tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ síí bọ oriṣa lásánlàsàn, tí àwọn pàápàá sì fi di eniyan lásán? +Wọn kò bèèrè pé, Níbo ni OLUWA wà,ẹni tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti,tí ó sìn wá la aṣálẹ̀ já,ilẹ̀ aṣálẹ̀ tí ó kún fún ọ̀gbun,ilẹ̀ ọ̀dá ati òkùnkùn biribiri,ilẹ̀ tí eniyan kìí là kọjá,tí ẹnikẹ́ni kì í gbé? +Mo mu yín wá sí ilẹ̀ tí ó lọ́ràá,pé kí ẹ máa gbádùn èso rẹ̀ ati àwọn nǹkan dáradára tí wọ́n wà ninu rẹ̀,ṣugbọn nígbà tí ẹ dé inú rẹ̀, ẹ sọ ilẹ̀ mi di aláìmọ́,ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra. +Àwọn alufaa kò bèèrè pé, ‘OLUWA dà?’Àwọn tí wọn ń ṣe àmójútó òfin kò mọ̀ mí,àwọn olórí ń dìtẹ̀ sí mi,àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ oriṣa Baali,wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa lásánlàsàn. +“Nítorí náà, mò ń ba yín rojọ́,n óo sì tún bá arọmọdọmọ yín rojọ́ pẹlu.”OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +Ìjà láàrin Jeremaya ati Paṣuri Alufaa. +Nígbà tí Paṣuri alufaa, ọmọ Imeri, tí ó jẹ́ olórí àwọn olùṣọ́ ilé OLUWA, gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremaya ń sọ, +Nítorí mò ń gbọ́ tí ọpọlọpọ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé,“Ìpayà wà lọ́tùn-ún lósì,ẹ lọ fẹjọ́ rẹ̀ sùn.Ẹ jẹ́ kí á fẹjọ́ rẹ̀ sùn.”Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń wí,tí wọn sì ń retí ìṣubú mi.Wọ́n ń sọ pé,“Bóyá yóo bọ́ sọ́wọ́ ẹlẹ́tàn,ọwọ́ wa yóo sì tẹ̀ ẹ́;a óo sì gbẹ̀san lára rẹ̀.” +Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu mi bíi jagunjagun tí ó bani lẹ́rù.Nítorí náà àwọn tí wọn ń lépa mi yóo kọsẹ̀,apá wọn kò ní ká mi.Ojú yóo tì wọ́n lọpọlọpọ nítorí wọn kò ní lè borí mi.Ẹ̀sín tí ẹnikẹ́ni kò ní gbàgbé yóo dé bá wọn títí lae. +OLUWA àwọn ọmọ ogun, ìwọ tíí dán olódodo wò,ìwọ tí o mọ ọkàn ati èrò eniyan.Gbẹ̀san lára wọn kí n fojú rí i,nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́. +Ẹ kọrin sí OLUWA,ẹ yin OLUWA.Nítorí pé ó gba ẹ̀mí aláìní sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣebi. +Ègún ni fún ọjọ́ tí a bí mi,kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má jẹ́ ọjọ́ ayọ̀. +Ègún ni fún ẹni tí ó yọ̀ fún baba mi,tí ó sọ fún un pé,“Iyawo rẹ ti bí ọmọkunrin kan fún ọ,tí ó mú inú rẹ̀ dùn.” +Kí olúwarẹ̀ dàbí àwọn ìlú tí OLUWA parun láìṣàánú wọn.Kí ó gbọ́ igbe lówùúrọ̀,ati ariwo ìdágìrì lọ́sàn-án gangan. +Nítorí pé kò pa mí ninu oyún,kí inú ìyá mi lè jẹ́ isà òkú fún mi.Kí n wà ninu oyún ninu ìyá mi títí ayé. +Kí ló dé tí wọn bí mi sáyé? Ṣé kí n lè máa fojú rí ìṣẹ́ ati ìbànújẹ́ ni?Kí gbogbo ọjọ́ ayé mi lè kún fún ìtìjú? +ó ní kí wọn lu Jeremaya, kí wọn kàn ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Bẹnjamini ti òkè, ní ilé OLUWA. +Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí Paṣuri tú Jeremaya sílẹ̀ ninu ààbà, Jeremaya wí fún un pé, “Kì í ṣe Paṣuri ni OLUWA pe orúkọ rẹ, ìpayà lọ́tùn-ún ati lósì ni OLUWA pè ọ́. +OLUWA ní, ‘N óo sọ ọ́ di ìpayà fún ara rẹ ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. Àwọn ọ̀tá yóo fi idà pa wọ́n níṣojú rẹ, n óo fi gbogbo ilẹ̀ Juda lé ọba Babiloni lọ́wọ́. Yóo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, yóo sì fi idà pa wọ́n. +Bákan náà, n óo da gbogbo ọrọ̀ ìlú yìí, ati gbogbo èrè iṣẹ́ tí wọ́n ṣe lé àwọn ará Babiloni lọ́wọ́, pẹlu gbogbo nǹkan olówó iyebíye wọn, ati gbogbo ìṣúra àwọn ọba Juda; gbogbo rẹ̀ ni àwọn ọ̀tá wọn, àwọn ará Babiloni yóo fogun kó, wọn yóo sì rù wọ́n lọ sí Babiloni. +Ní ti ìwọ Paṣuri, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ, wọn óo ko yín ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni ẹ óo kú sí, ibẹ̀ ni wọ́n óo sì sin yín sí; àtìwọ, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ò ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.’ ” +OLUWA, o tàn mí jẹ, mo sì gba ẹ̀tàn;o ní agbára jù mí lọ, o sì borí mi.Mo di ẹni ẹ̀sín láti àárọ̀ títí di alẹ́,gbogbo eniyan ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. +Gbogbo ìgbà tí mo bá ti sọ̀rọ̀, ni mò ń kígbe pé,“Ogun ati ìparun dé!”Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń kéde sọ mí di ẹni yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru. +Ṣugbọn nígbàkúùgbà tí mo bá wí pé n kò ní dárúkọ rẹ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀ mọ́,ọ̀rọ̀ rẹ a máa jó mi ninu bí iná,a sì máa ro mí ninu egungun.Mo gbìyànjú títí pé kí n pa á mọ́ra,ṣugbọn kò ṣeéṣe. +Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìṣubú Jerusalẹmu. +Ọ̀rọ̀ tí Jeremaya gbọ́ lẹ́nu OLUWA nìyí nígbà tí ọba Sedekaya rán Paṣuri, ọmọ Malikaya, ati alufaa Sefanaya, ọmọ Maaseaya, sí i; +Nítorí pé mo ti dójú lé ìlú yìí láti ṣe ní ibi, kì í ṣe fún rere. Ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ ọba Babiloni, yóo sì dá iná sun ún, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA ní kí n sọ fún ìdílé ọba Juda pé òun OLUWA ní, +“Ẹ̀yin ará ilé Dafidi!Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ní òwúrọ̀,ẹ máa gba ẹni tí a jà lólè lọ́wọ́ aninilára,kí ibinu èmi OLUWA má baà ru jáde, nítorí iṣẹ́ ibi yín,kí ó sì máa jó bíi iná,láìsí ẹni tí yóo lè pa á.” +OLUWA ní,“Ẹ wò ó, mo dojú ìjà kọ yín,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé àfonífojì,tí ó dàbí àpáta tí ó yọ sókè ju pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí pé,‘Ta ló lè dojú ìjà kọ wá?Àbí ta ló lè wọ inú odi ìlú wa?’ +N óo jẹ yín níyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ yín;èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.N óo dáná sun igbó yín,yóo sì jó gbogbo ohun tí ó wà ní agbègbè yín ní àjórun.” +tí ọba Sedekaya ní, “Ẹ sọ fún Jeremaya pé kí ó bá wa ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA nípa Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí ó gbógun tì wá; bóyá OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún wa, kí Nebukadinesari kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ wa.” +Jeremaya sọ fun awọn tí wọn rán sí i, +kí wọ́n sọ fún Sedekaya pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, “N óo gba àwọn ohun ìjà tí ó wà lọ́wọ́ yín, tí ẹ fi ń bá ọba Babiloni ati àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì yín lẹ́yìn odi jà, n óo dá wọn pada sí ààrin ìlú, n óo sì dojú wọn kọ yín. +Èmi fúnra mi ni n óo ba yín jà. Ipá ati agbára, pẹlu ibinu ńlá, ati ìrúnú gbígbóná ni n óo fi ba yín jà. +N óo fi àjàkálẹ̀ àrùn ńlá kọlu àwọn ará ìlú yìí, ati eniyan ati ẹranko ni yóo sì kú. +Lẹ́yìn náà n óo mú Sedekaya ọba Juda, ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn, ogun, ati ìyàn, bá pa kù ní ìlú yìí, n óo fi wọ́n lé Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́, òun ati àwọn ọ̀tá tí ń wá ọ̀nà láti pa wọ́n. Ọba Babiloni yóo fi idà pa wọ́n, kò ní ṣàánú wọn, kò sì ní dá ẹnikẹ́ni sí.” +OLUWA ní, “Sọ fún àwọn eniyan yìí pé èmi OLUWA ni mo la ọ̀nà meji níwájú wọn: ọ̀nà ìyè ati ọ̀nà ikú. +Ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn yóo pa ẹni tí ó bá dúró sinu ìlú yìí; ṣugbọn ẹni tí ó bá jáde tí ó sì fa ara rẹ̀ fún àwọn ará Kalidea, tí ó gbé ogun tì yín, yóo yè, yóo dàbí ẹni tó ja àjàbọ́. +Iṣẹ́ tí Jeremaya Jẹ́ fún Ìdílé Ọba Juda. +OLUWA sọ fún mi pé, kí n lọ sí ilé ọba Juda kí n sọ fún un níbẹ̀ pé, +Ẹ̀yin ará Juda,ẹ má sọkún nítorí ọba tí ó kú,ẹ má sì dárò rẹ̀.Ọba tí ń lọ sí ìgbèkùn ni kí ẹ sọkún fún,nítorí pé yóo lọ, kò sì ní pada wá mọ́láti fojú kan ilẹ̀ tí a bí i sí. +Nítorí pé OLUWA sọ nípa Joahasi, ọba Juda, ọmọ Josaya, tí ó jọba dípò Josaya baba rẹ̀, tí ó sì jáde kúrò ní ibí yìí pé, “Kò ní pada sibẹ mọ́. +Ibi tí wọn mú un ní ìgbèkùn lọ ni yóo kú sí; kò ní fi ojú rí ilẹ̀ yìí mọ́.” +Ẹni tí ó ń fi aiṣododo kọ́ ilé rẹ̀ gbé,tí ó ń fi ọ̀nà èrú kọ́ òrùlé rẹ̀.Tí ó mú ọmọ ẹnìkejì rẹ̀ sìn lọ́fẹ̀ẹ́,láìsan owó iṣẹ́ rẹ̀ fún un. +Ègbé ni fún ẹni tí ó wí pé,“N óo kọ́ ilé ńlá fún ara mi,ilé tí ó ní yàrá ńláńlá lókè rẹ̀.”Ó bá yọ àwọn fèrèsé sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́.Ó fi igi kedari bo ara ògiri rẹ̀,ó wá fi ọ̀dà pupa kùn ún. +Ṣé ilé kedari tí o kọ́ ni ó sọ ọ́ di ọba?Wo baba rẹ, ṣé kò rí jẹ ni,tabi kò rí mu?Ṣebí �� ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo,ṣebí ó sì dára fún un. +Ẹjọ́ ẹ̀tọ́ níí dá fún talaka ati aláìní,ohun gbogbo sì ń lọ dáradára.Ṣebí èyí ni à ń pè ní kí eniyan mọ OLUWA?OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +Ṣugbọn níbi èrè aiṣododo nìkan ni ojú ati ọkàn yín ń wà,níbi kí ẹ máa pa aláìṣẹ̀, kí ẹ máa ni eniyan lára,kí ẹ sì máa hùwà ìkà. +Nítorí náà, OLUWA sọ nípa Jehoiakimu, ọba Juda, ọmọ Josaya pé, wọn kò ní dárò rẹ̀, pé,“Ó ṣe, arakunrin mi!”Tabi pé, “Ó ṣe, arabinrin mi!”Wọn kò ní ké pé,“Ó ṣe, oluwa mi!” Tabi pé, “Ó ṣe! Áà! Kabiyesi!” +Bí ẹni ń ṣe òkú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni wọ́n óo ṣe òkú rẹ̀;ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu ni wọn yóo wọ́ ọ jù sí.Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, +“Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, ìwọ ọba Juda, tí o jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ ati àwọn eniyan rẹ, tí wọn ń gba àwọn ẹnubodè wọnyi wọlé: +ẹ gun orí òkè Lẹbanoni lọ, kí ẹ kígbe.Ẹ dúró lórí òkè Baṣani, kí ẹ pariwo gidigidi,ẹ kígbe láti orí òkè Abarimu,nítorí pé a ti pa gbogbo àwọn alájọṣe yín run. +OLUWA bá yín sọ̀rọ̀ nígbà tí nǹkan ń dára fun yín,ṣugbọn ẹ sọ pé ẹ kò ní gbọ́.Bẹ́ẹ̀ ni ẹ tí ń ṣe láti kékeré yín,ẹ kì í gbọ́rọ̀ sí OLUWA lẹ́nu. +Afẹ́fẹ́ yóo fẹ́ gbogbo àwọn olórí yín lọ,àwọn olólùfẹ́ yín yóo lọ sí ìgbèkùn.Ojú yóo wá tì yín,ẹ óo sì di ẹni ẹ̀tẹ́,nítorí gbogbo ibi tí ẹ̀ ń ṣe. +Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Lẹbanoni,tí ẹ kọ́ ilé yín sí ààrin igi kedari.Ẹ óo kérora nígbà tí ara bá ń ni yín,tí ara ń ni yín bíi ti obinrin tí ń rọbí ọmọ! +OLUWA sọ fún Jehoiakini ọba, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, pé, “Mo fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ ni òrùka èdìdì ọwọ́ ọ̀tún mi, +n óo bọ́ ọ kúrò, n óo sì fi ọ́ lé Nebukadinesari ọba Babiloni, ati àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí rẹ, tí ẹ̀rù wọn sì ń bà ọ́. +N óo wọ́ ìwọ ati ìyá tí ó bí ọ jù sí ilẹ̀ àjèjì, tí kì í ṣe ibi tí wọ́n bí ọ sí, ibẹ̀ ni ẹ óo kú sí. +Ṣugbọn ilẹ̀ tí ọkàn yín fẹ́ pada sí, ẹ kò ní pada sibẹ mọ́.” +Ṣé àfọ́kù ìkòkò tí ẹnikẹ́ni kò kà kún ni Jehoiakini?Àbí o ti di ohun èlò àlòpatì?Kí ló dé tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀fi di ẹni tí a kó lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀ rí? +Ilẹ̀! Ilẹ̀!Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ! +Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo, kí ẹ máa gba ẹni tí wọn ń jà lólè lọ́wọ́ àwọn aninilára. Ẹ má hùwà burúkú sí àwọn àlejò, tabi àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó. Ẹ má ṣe wọ́n níbi, ẹ má sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibi mímọ́ yìí. +Ó ní, “Ẹ kọ orúkọ ọkunrin yìí sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ,ẹni tí kò ní ṣe rere kan ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀;nítorí pé kò sí ọ̀kankan ninu àwọn ọmọ rẹ̀tí yóo rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi,Ìdílé rẹ̀ kò sì ní jọba mọ ní Juda.” +Nítorí pé bí ẹ bá fi tọkàntọkàn fetí sí ọ̀rọ̀ mi, àwọn ọba yóo máa wọlé, wọn yóo sì máa jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi. Wọn yóo máa gun ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn, ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn eniyan. +Ṣugbọn bí ẹ kò bá gba ohun tí mo wí, mo ti fi ara mi búra pé ilẹ̀ yìí yóo di ahoro. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA sọ nípa ìdílé ọba Juda pé,“Bíi Gileadi ni o dára lójú mi,ati bí orí òkè Lẹbanoni.Ṣugbọn sibẹ, dájúdájú, n óo sọ ọ́ di aṣálẹ̀;o óo sì di ìlú tí ẹnikẹ́ni kò ní gbé. +N óo kó àwọn apanirun tí yóo pa ọ́ run wá,olukuluku yóo wá pẹlu ohun ìjà rẹ̀.Wọn óo gé àwọn tí wọn dára jùlọ ninu àwọn igi Kedari yín,wọn óo sì sun wọ́n níná. +“Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni yóo máa gba ìlú yìí kọjá; wọn yóo sì máa bi ara wọn pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi ṣe báyìí sí ìlú ńlá yìí?’ +Àwọn eniyan yóo sì máa dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọ́n kọ majẹmu OLUWA Ọlọrun wọn sílẹ̀ ni, wọ́n ń bọ oriṣa, wọ́n sì ń sìn wọ́n.’ ” +Ìrètí Ọjọ́ Iwájú. +OLUWA ní, “Àwọn olùṣọ́-aguntan tí wọn ń tú àwọn agbo aguntan mi ká, tí wọn ń run wọ́n gbé!” +Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún àgbèrè ẹ̀sìn,ọ̀nà ibi ni wọ́n ń tọ̀,wọn kò sì lo agbára wọn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́nítorí ègún, ilẹ̀ ti di gbígbẹgbogbo pápá oko ló ti gbẹ. +Ati wolii, ati alufaa, ìwà burúkú ni wọ́n ń hù,ní ilé mi pàápàá mo rí iṣẹ́ ibi wọn,èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Nítorí náà ọ̀nà wọn yóo dàbí ọ̀nà tí ń yọ̀ ninu òkùnkùn,a óo tì wọ́n sinu rẹ̀, wọn yóo sì ṣubú,nítorí n óo mú kí ibi bá wọn ní ọdún ìjìyà wọn. +Mo rí nǹkankan tí ó burú lọ́wọ́ àwọn wolii Samaria:Ẹ̀mí oriṣa Baali ni wọ́n fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀;wọ́n sì ń ṣi àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, lọ́nà. +Mo rí nǹkankan tí ó bani lẹ́rù lọ́wọ́ àwọn wolii Jerusalẹmu: Wọ́n ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn,wọ́n ń hùwà èké;wọ́n ń ran àwọn ẹni ibi lọ́wọ́,kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi rẹ̀.Gbogbo wọn ti di ará Sodomu lójú mi,àwọn ará Jerusalẹmu sì dàbí àwọn ará Gomora. +Nítorí náà OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa àwọn wolii pé:N óo fún wọn ní ewé igi kíkorò jẹ,n óo fún wọn ní omi májèlé mu.Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ àwọn wolii Jerusalẹmuni ìwà burúkú ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ yìí. +OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín, tí wọ́n ń mu yín gbẹ́kẹ̀lé irọ́. Ohun tí wọn fẹ́ lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ, kì í ṣe ẹnu èmi OLUWA ni wọ́n ti gbọ́ ọ. +Wọ́n ń sọ lemọ́lemọ́ fún àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí pé, yóo dára fún wọn. Wọ́n ń wí fún gbogbo àwọn tí wọn ń tẹ̀lé àìgbọràn ọkàn wọn pé ibi kò ní bá wọn.” +Mo ní, “Èwo ninu wọn ló wà ninu ìgbìmọ̀ OLUWA tí ó ti ṣe akiyesi tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Èwo ninu wọn ni ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sì gbà á gbọ́? +Ẹ wo ibinu OLUWA bí ó ṣe ń jà bí ìjì! Ó ti fa ibinu yọ. Ó sì ń jà bí ìjì líle. Yóo tú dà sí orí àwọn eniyan burúkú. +Nítorí náà, OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn tí ó fi ṣọ́ àwọn eniyan rẹ̀, láti máa bojútó wọn pé, “Ẹ ti tú àwọn aguntan mi ká, ẹ ti lé wọn dànù, ẹ kò sì tọ́jú wọn. N óo wá ṣe ìdájọ́ fun yín nítorí iṣẹ́ ibi yín, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Inú OLUWA kò ní rọ̀ títí yóo fi ṣe ohun tí ó pinnu lọ́kàn rẹ̀. Yóo ye wọn nígbà tí ọjọ́ ìkẹyìn bá dé.” +OLUWA ní, “N kò rán àwọn wolii níṣẹ́, sibẹsibẹ aré ni wọ́n ń sá lọ jíṣẹ́. N kò bá wọn sọ̀rọ̀, sibẹsibẹ wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. +Bí wọn bá ti bá mi pé ní ìgbìmọ̀ ni, wọn ìbá kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn eniyan mi, wọn ìbá yí wọn pada kúrò lọ́nà ibi tí wọn ń rìn, ati iṣẹ́ ibi tí wọn ń ṣe. +“Ṣé nítòsí nìkan ni mo ti jẹ́ Ọlọrun ni, èmi kì í ṣe Ọlọrun ọ̀nà jíjìn? +Ǹjẹ́ ẹnìkan lè sápamọ́ sí ìkọ̀kọ̀ kan tí n kò fi ní rí i? Kì í ṣe èmi ni mo wà ní gbogbo ọ̀run tí mo sì tún wà ní gbogbo ayé? +Mo gbọ́ ohun tí àwọn wolii tí wọn ń fi orúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ń sọ, tí wọn ń sọ pé, àwọn lá àlá, àwọn lá àlá! +Irọ́ yóo ti pẹ́ tó lọ́kàn àwọn wolii èké tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn. +Wọ́n ṣebí àwọn lè fi àlá tí olukuluku wọn ń rọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀ mú àwọn eniyan mi gbàgbé orúkọ mi, bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé mi, tí wọn ń tẹ̀lé oriṣa Baali. +Kí àwọn wolii tí wọn lá àlá máa rọ́ àlá wọn, ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ó sọ ọ́ pẹlu òtítọ́. Báwo ni a ṣe lè fi ìyàngbò wé ọkà? +Ṣebí bí iná ni ọ̀rọ̀ mi rí, ati bí òòlù irin tíí fọ́ àpáta sí wẹ́wẹ́? +N óo kó àwọn tí wọ́n kù ninu àwọn aguntan mi jọ láti gbogbo ibi tí mo lé wọn lọ. N óo kó wọn pada sinu agbo wọn. Wọn óo bímọ lémọ, wọn óo sì máa pọ̀ sí i. +Nítorí náà, mo dojú ìjà kọ àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ tí wọn gbọ́ lẹ́nu ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi ni mo sọ ọ́. +Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ ti ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlá irọ́, tí wọn ń rọ́ àlá irọ́ wọn, tí wọn fí ń ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà pẹlu irọ́ ati ìṣekúṣe wọn, nígbà tí n kò rán wọn níṣẹ́, tí n kò sì fún wọn láṣẹ. Nítorí náà wọn kò ṣe àwọn eniyan wọnyi ní anfaani kankan. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Bí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọnyi, tabi wolii kan, tabi alufaa kan, bá bi ọ́ léèrè pé, “Kí ni iṣẹ́ tí OLUWA rán?” Wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin gan-an ni ẹ jẹ́ ẹrù. OLUWA sì ní òun óo gbé yín sọnù.” +Bí wolii kan tabi alufaa kan tabi ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan wọnyi bá wí pé òun ń jẹ́ iṣẹ́ OLUWA, n óo jẹ olúwarẹ̀ ati ilé rẹ̀ níyà. +Báyìí ni kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa wí fún ẹnìkejì rẹ, ati fún arakunrin rẹ̀, “Kí ni ìdáhùn OLUWA?” tabi “Kí ni OLUWA wí?” +Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nuba ẹrù OLUWA mọ́. Nítorí pé èrò ọkàn olukuluku ni ẹrù OLUWA lójú ara rẹ̀; ẹ sì ń yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun alààyè po, ọ̀rọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wa. +Bí ẹ óo ti máa bèèrè lọ́wọ́ àwọn wolii ni pé, “Kí ni ìdáhùn tí OLUWA fún ọ?” Tabi, “Kí ni OLUWA wí?” +Ṣugbọn bí ẹ bá mẹ́nu ba “Ẹrù OLUWA,” lẹ́yìn tí mo ti ranṣẹ si yín pé ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nu bà á mọ́, +tìtorí rẹ̀, n óo sọ yín sókè, n óo sì gbe yín sọnù kúrò níwájú mi, àtẹ̀yin, àtìlú tí mo fi fún ẹ̀yin, ati àwọn baba ńlá yín. +N óo wá fún wọn ní olùṣọ́ mìíràn tí yóo tọ́jú wọn. Ẹ̀rù kò ní bà wọ́n mọ́, wọn kò ní fòyà, ọ̀kankan ninu wọn kò sì ní sọnù, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +N óo mú ẹ̀gàn ati ẹ̀sín ba yín, tí ẹ kò ní gbàgbé títí ayérayé. +“Wò ó! Àkókò kan ń bọ̀, tí n óo gbé Ẹ̀ka olódodo kan dìde ninu ìdílé Dafidi. Yóo jọba, yóo hùwà ọlọ́gbọ́n, yóo sì ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ náà. +Juda yóo rí ìgbàlà ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo sì wà láìléwu. Orúkọ tí a óo máa pè é ni ‘OLUWA ni òdodo wa.’ +“Nítorí náà àkókò kan ń bọ̀, tí wọn kò ní máa búra ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti mọ́, +ṣugbọn tí wọn yóo máa wí pé, ‘Ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ ilé Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá, ati gbogbo ilẹ̀ tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ, tí ó sì mú wọn pada sí ilẹ̀ wọn.’ Wọn óo wá máa gbé orí ilẹ̀ wọn nígbà náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Ọkàn mi bàjẹ́ nítorí àwọn wolii,gbogbo ara mi ń gbọ̀n.Mo dàbí ọ̀mùtí tí ó ti mu ọtí yó,mo dàbí ẹni tí ọtí ń pa,nítorí OLUWA, ati nítorí ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀. +Apẹ̀rẹ̀ Èso Ọ̀pọ̀tọ́ Meji. +Lẹ́yìn tí Nebukadinesari, ọba Babiloni ti kó Jehoiakini ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu kúrò ní ìlú Jerusalẹmu lọ sí Babiloni, pẹlu àwọn ìjòyè Juda, ati àwọn oníṣẹ́ ọnà, ati àwọn alágbẹ̀dẹ, OLUWA fi ìran yìí hàn mí. Mo rí apẹ̀rẹ̀ èso ọ̀pọ̀tọ́ meji níwájú ilé OLUWA. +Ó ní òun óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, títí wọn yóo fi kú tán, tí kò ní ku ẹyọ ẹnìkan lórí ilẹ̀ tí òun fún àwọn ati àwọn baba ńlá wọn. +Èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó wà ninu apẹ̀rẹ̀ kinni dára gbáà, ó dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó kọ́kọ́ pọ́n. Èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó wà ninu apẹ̀rẹ̀ keji ti rà patapata tóbẹ́ẹ̀ tí kò ṣe é jẹ. p +OLUWA bá bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí?”Mo ní, “Èso ọ̀pọ̀tọ́ ni, àwọn tí ó dára, dára gan-an, àwọn tí kò sì dára bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ṣe é jẹ.” +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, àwọn tí mo ti mú kí á kó lẹ́rú láti ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, ni pé, n óo kà wọ́n sí rere gẹ́gẹ́ bí àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára wọnyi. +N óo fi ojurere wò wọ́n, n óo kó wọn pada wá sí ilẹ̀ yìí. N óo fìdí wọn múlẹ̀, n kò sì ní pa wọ́n run. N óo gbé wọn ró, n kò ní fà wọ́n tu, +n óo sì fún wọn ní òye láti mọ̀ pé èmi ni OLUWA. Wọn yóo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn; nítorí tí wọn yóo fi tọkàntọkàn yipada sí mi.” +Ṣugbọn ohun tí OLUWA sọ nípa Sedekaya ọba Juda, ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati àwọn ará Jerusalẹmu tí wọ́n kù ní ilẹ̀ yìí, ati àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti, ni pé òun óo ṣe wọ́n bí èso burúkú tí kò ṣe é jẹ. +Ó ní òun óo sọ wọ́n di ẹni àríbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba ayé. Wọn óo di ẹni ẹ̀gàn, ẹni ẹ̀sín, ẹni yẹ̀yẹ́ ati ẹni tí a fi ń ṣẹ́ èpè ní gbogbo ibi tí òun óo tì wọ́n lọ. +Àwọn Ọ̀tá láti Ìhà Àríwá. +Ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya jọba ní Juda, tí ó jẹ́ ọdún kinni tí Nebukadinesari jọba Babiloni, Jeremaya wolii gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA nípa gbogbo àwọn ará Juda. +N óo pa ìró ayọ̀ ati ẹ̀rín rẹ́ láàrin wọn, ẹnìkan kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo tuntun mọ́. A kò ní gbọ́ ìró ọlọ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí iná fìtílà mọ́. +Gbogbo ilẹ̀ yìí yóo di àlàpà ati aṣálẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì sin ọba Babiloni fún aadọrin ọdún. +Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, n óo jẹ ọba Babiloni ati orílẹ̀-èdè rẹ̀, ati ilẹ̀ àwọn ará Kalidea níyà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo sì sọ ibẹ̀ di àlàpà títí ayé. +N óo mú gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú tí mo ti sọ nípa ilẹ̀ náà ṣẹ, ati gbogbo ohun tí a kọ sinu ìwé yìí, àní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jeremaya sọ nípa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. +Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba alágbára yóo sọ àwọn ará Babiloni pàápàá di ẹrú, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san ìṣe wọn ati iṣẹ́ ọwọ́ wọn.” +OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún mi pé, “Gba ife ọtí ibinu yìí lọ́wọ́ mi, kí o fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí n óo rán ọ sí mu. +Wọn yóo mu ún, wọn yóo sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, wọn yóo máa ṣe bí aṣiwèrè nítorí ogun tí n óo rán sí ààrin wọn.” +Mo bá gba ife náà lọ́wọ́ OLUWA, mo sì fún gbogbo orílẹ̀-èdè tí OLUWA rán mi sí mu: +Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, àwọn ọba ilẹ̀ Juda ati àwọn ìjòyè wọn, kí wọn lè di ahoro ati òkítì àlàpà, nǹkan àrípòṣé ati ohun tí à ń fi í ṣépè, bí ó ti rí ní òní yìí. +N óo fún Farao, ọba Ijipti mu, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ +Jeremaya sọ ọ̀rọ̀ náà fún gbogbo àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu. +ati àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin wọn. N óo fún gbogbo àwọn ọba Usi mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini, (Aṣikeloni, Gasa, Ekironi ati àwọn tí wọ́n kù ní Aṣidodu). +N óo fún Edomu mu, ati Moabu, ati àwọn ọmọ Amoni; +ati gbogbo àwọn ọba Tire, ati àwọn ọba Sidoni, ati gbogbo àwọn ọba erékùṣù tí ó wà ní òdìkejì òkun. +N óo fún Dedani mu, ati Tema, ati Busi ati gbogbo àwọn tí wọn ń gé ẹsẹ̀ irun wọn. +N óo fún gbogbo àwọn ọba Arabia mu ati gbogbo àwọn ọba oríṣìíríṣìí ẹ̀yà tí wọn ń gbé aṣálẹ̀. +N óo fún gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Simiri mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Elamu ati gbogbo àwọn ti ilẹ̀ Media; +ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ àríwá, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ati àwọn tí wọ́n wà lọ́nà jíjìn. N óo sì fún àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ ayé mu pẹlu. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn bá ti mu tiwọn tán, ọba Babiloni yóo wá mu tirẹ̀. +OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí ẹ mu ọtí kí ẹ yó, kí ẹ sì máa bì, ẹ ṣubú lulẹ̀ kí ẹ má dìde mọ́; nítorí ogun tí n óo jẹ́ kí ó bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin yín. +Bí wọn bá kọ̀ tí wọn kò gba ife náà lọ́wọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, wí fún wọn pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní wọ́n gbọdọ̀ mu ún ni! +Nítorí pé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ibi ṣẹlẹ̀ sórí ìlú tí à ń fi orúkọ mi pè yìí, ǹjẹ́ ẹ lè lọ láìjìyà bí? Rárá o, ẹ kò ní lọ láìjìyà nítorí pé mo ti pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ ayé kú ikú idà, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Ó ní, “Fún ọdún mẹtalelogun, láti ọdún kẹtala tí Josaya ọmọ Amoni ti jọba Juda, títí di ọjọ́ òní, ni OLUWA ti ń bá mi sọ̀rọ̀, tí mo sì ti ń sọ ọ́ fun yín lemọ́lemọ́, ṣugbọn tí ẹ kò sì gbọ́. +“Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí fún wọn pé:‘OLUWA yóo bú ramúramù láti òkè,yóo pariwo láti ibi mímọ́ rẹ̀.Yóo bú ramúramù mọ́ àwọn eniyan inú agbo rẹ̀.Yóo kígbe mọ́ gbogbo aráyé bí igbe àwọn tí ń tẹ àjàrà. +Ariwo náà yóo kàn dé òpin ayé,nítorí pé OLUWA ní ẹjọ́ láti bá àwọn orílẹ̀-èdè rò.Yóo dá gbogbo eniyan lẹ́jọ́,yóo fi idà pa àwọn eniyan burúkú,OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.’ ” +OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ibi yóo máa ṣẹlẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji, ìjì ńlá yóo sì jà láti òpin ayé wá. +Òkú àwọn tí OLUWA yóo pa ní ọjọ́ náà yóo kún inú ayé láti òpin kan dé ekeji. Ẹnikẹ́ni kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, kò sí ẹni tí yóo gbé òkú wọn nílẹ̀; wọn kò ní sin wọ́n. Wọn yóo dàbí ìgbẹ́ lórí ilẹ̀. +Ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ kígbe. Ẹ̀yin oluwa àwọn agbo ẹran, ẹ máa yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú nítorí àkókò tí a óo pa yín, tí a óo sì tu yín ká ti tó, ẹ óo sì ṣubú lulẹ̀ bí ẹran àbọ́pa. +Kò ní sí ààbò mọ́ fún àwọn olùṣọ́-aguntan, kò ní sí ọ̀nà ati sá àsálà fún àwọn oluwa àwọn agbo ẹran. +Ẹ gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-aguntanati ẹkún ẹ̀dùn ti àwọn oluwa agbo ẹran;nítorí OLUWA ń ba ibùjẹ ẹran wọn jẹ́. +Pápá oko tútù tí ìbẹ̀rù kò sí níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ti di ahoronítorí ibinu gbígbóná OLUWA. +Bíi kinniun tí ó fi ihò rẹ̀ sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fi àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀,ilẹ̀ wọn sì ti di ahoronítorí idà apanirun ati ibinu gbígbóná OLUWA. +Ẹ kò fetí sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà gbogbo ni OLUWA ń rán àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀, si yín, tí wọn ń sọ fun yín pé +kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀ ati iṣẹ́ ibi tí ó ń ṣe, kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí OLUWA fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín títí lae, láti ìgbà àtijọ́. +Wọ́n ní kí ẹ má wá àwọn oriṣa lọ, kí ẹ má bọ wọ́n, kí ẹ má sì sìn wọ́n. Wọ́n ní kí ẹ má fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú un bínú, kí ó má baà ṣe yín ní ibi.” +OLUWA alára ní, “Mo wí, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ tèmi; kí ẹ lè fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, fún ìpalára ara yín.” +Ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, +n óo ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àríwá wá. N óo ranṣẹ sí Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ mi, n óo jẹ́ kí wọn wá dó ti ilẹ̀ yìí, ati àwọn tí ń gbé ibẹ̀. Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ yìí ni n óo parun patapata, tí n óo sọ di àríbẹ̀rù, ati àrípòṣé, ati ohun ẹ̀gàn títí lae. +A Pe Jeremaya Lẹ́jọ́. +Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, ọmọ Josaya, +Nígbà tí àwọn ìjòyè Juda gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n lọ sí ilé OLUWA láti ààfin ọba, wọ́n sì jókòó ní Ẹnu Ọ̀nà Titun tí ó wà ní ilé OLUWA. +Àwọn alufaa ati àwọn wolii bá sọ fún àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan pé, “Ẹjọ́ ikú ni ó yẹ kí a dá fún ọkunrin yìí nítorí àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ń sọ nípa ìlú yìí, ẹ̀yin náà sá fi etí ara yín gbọ́.” +Jeremaya bá sọ fún àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan pé, “OLUWA ni ó rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí ẹ gbọ́ sí ilé yìí ati ìlú yìí. +Nítorí náà, ẹ tún ọ̀nà yín ṣe, ẹ pa ìṣe yín dà, kí ẹ sì gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu, yóo sì yí ọkàn rẹ̀ pada kúrò ninu ibi tí ó sọ pé òun yóo ṣe sí i yín. +Ní tèmi, mo wà lọ́wọ́ yín, ohun tí ó bá dára lójú yín ni kí ẹ fi mí ṣe. +Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé bí ẹ bá pa mí, ẹ óo fa ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sórí ara yín, ati ìlú yìí ati àwọn ará ìlú yìí, nítorí pé nítòótọ́ ni OLUWA rán mi pé kí n sọ gbogbo ohun tí mo sọ kí ẹ gbọ́.” +Àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan bá sọ fún àwọn alufaa ati àwọn wolii pé, “Ẹjọ́ ikú kò tọ́ sí ọkunrin yìí, nítorí pé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa ni ó fi ń bá wa sọ̀rọ̀.” +Àwọn kan ninu àwọn àgbààgbà ìlú dìde, wọ́n bá gbogbo ìjọ eniyan sọ̀rọ̀; wọ́n ní, +“Ní ìgbà Hesekaya ọba Juda, Mika ará Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún gbogbo àwọn ará Juda pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘A óo kọ Sioni bí ilẹ̀ oko,Jerusalẹmu yóo di òkítì àlàpà;òkè ilé yìí yóo sì di igbó kìjikìji.’ +Ǹjẹ́ Hesekaya ati gbogbo eniyan Juda pa Mika bí? Ṣebí OLUWA yí ibi tí ó ti pinnu láti ṣe sí wọn pada, nítorí pé Hesekaya bẹ̀rù OLUWA ó sì wá ojurere rẹ̀. Ṣugbọn ní tiwa ibi ńláńlá ni a fẹ́ fà lé orí ara wa yìí.” +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní, “Dúró sí gbọ̀ngàn ilé OLUWA, kí o sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo pa láṣẹ fún ọ pé kí o sọ fún gbogbo àwọn ará ìlú Juda tí wọn ń wá jọ́sìn níbẹ̀. Má fi ọ̀rọ̀ kankan pamọ́. +Ọkunrin kan tún wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Uraya, ọmọ Ṣemaaya, láti ìlú Kiriati Jearimu. Òun náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ yìí ati ilẹ̀ wa bí Jeremaya ti sọ yìí. +Nígbà tí ọba Jehoiakimu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati àwọn ìjòyè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba wá ọ̀nà láti pa á. Nígbà tí Uraya gbọ́, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí ilẹ̀ Ijipti. +Ṣugbọn ọba Jehoiakimu rán Elinatani, ọmọ Akibori, ati àwọn ọkunrin kan lọ sí Ijipti, +wọ́n mú Uraya jáde ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n mú un tọ ọba Jehoiakimu wá. Ọba Jehoiakimu fi idà pa á, ó sì ju òkú rẹ̀ sí ibi tí wọn ń sin àwọn talaka sí. +Ṣugbọn Ahikamu ọmọ Ṣafani fọwọ́ sí ọ̀rọ̀ mi, kò sì jẹ́ kí á fà mí lé àwọn eniyan lọ́wọ́ láti pa. +Ó ṣeéṣe kí wọ́n gbọ́, kí olukuluku wọn sì yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀; kí n lè yí ọkàn mi pada nípa ibi tí mo fẹ́ ṣe sí wọn nítorí iṣẹ́ burúkú wọn. +“Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA ní bí wọn kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, kí wọn máa pa òfin tí mo gbé kalẹ̀ fún wọn mọ́, +kí wọn sì máa gbọ́ràn sí àwọn iranṣẹ mi lẹ́nu, ati àwọn wolii mi tí mò ń rán sí wọn léraléra, bí wọn kò tilẹ̀ kà wọ́n sí, +nítorí náà ni n óo ṣe ṣe ilé yìí bí mo ti ṣe Ṣilo; n óo sì sọ ìlú yìí di ohun tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóo máa fi gégùn-ún.” +Àwọn alufaa, àwọn wolii ati gbogbo àwọn eniyan gbọ́ tí Jeremaya ń sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ilé OLUWA. +Nígbà tí ó sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un pé kí ó sọ fún gbogbo àwọn eniyan náà tán, gbogbo wọn rá a mú, wọ́n ní, “Kíkú ni o óo kú! +Kí ló dé tí o fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLUWA pé ‘Ilé yìí yóo dàbí Ṣilo, ati pé ìlú yìí yóo di ahoro, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbébẹ̀ mọ́?’ ” Gbogbo eniyan bá pé lé Jeremaya lórí ninu ilé OLUWA. +Jeremaya Kọrùn Bọ Àjàgà. +Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda, ọmọ Josaya, OLUWA bá èmi Jeremaya sọ̀rọ̀; ó ní: +Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín, wọ́n fẹ́ kí á ko yín jìnnà sí ilẹ̀ yín ni. N óo le yín jáde; ẹ óo sì ṣègbé. +Ṣugbọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti ọrùn ara rẹ̀ bọ àjàgà ọba Babiloni, tí ó sì ń sìn ín, n óo fi sílẹ̀ lórí ilẹ̀ rẹ̀, kí ó lè máa ro ó, kí ó sì máa gbé ibẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Iṣẹ́ yìí kan náà ni mo jẹ́ fún Sedekaya ọba Juda. Mo ní, “Fi ọrùn rẹ sinu àjàgà ọba Babiloni, kí o sin òun ati àwọn eniyan rẹ̀, kí o lè wà láàyè. +Kí ló dé tí ìwọ ati àwọn eniyan rẹ fẹ́ kú ikú idà, ikú ìyàn ati ikú àjàkálẹ̀ àrùn bí OLUWA ti wí pé yóo rí fún orílẹ̀-èdè tí ó bá kọ̀ tí kò bá sin ọba Babiloni? +Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń wí fun yín pé ẹ kò ní ṣe ẹrú ọba Babiloni, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín. +OLUWA ní òun kò rán wọn níṣẹ́. Wọ́n kàn ń fi orúkọ òun sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni, kí òun lè le yín jáde, kí ẹ sì ṣègbé, àtẹ̀yin àtàwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín.” +Lẹ́yìn náà, mo bá àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, mo ní, “OLUWA sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín tí wọn ń wí fun yín pé wọn kò ní pẹ́ kó àwọn ohun èlò ilé èmi OLUWA pada wá láti Babiloni. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín. +Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ wọn. Ẹ sin ọba Babiloni, kí ẹ lè wà láàyè. Kí ló dé tí ìlú yìí yóo fi di ahoro? +Bí wọn bá jẹ́ wolii nítòótọ́, bí ó bá jẹ́ pé èmi OLUWA ni mo fi ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu, ẹ ní kí wọn gbadura sí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, kí n má jẹ́ kí wọ́n kó àwọn ohun èlò tí ó kù ní ilé OLUWA ati ní ààfin ọba Juda ati ní Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.” +Àwọn ohun èlò kan ṣẹ́kù ninu ilé OLUWA, àwọn bíi: òpó ilé, ati agbada omi tí a fi idẹ ṣe, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó kù ninu ìlú yìí, +“Ṣe àjàgà kan pẹlu okùn rẹ̀ kí o sì fi bọ ara rẹ lọ́rùn. +tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, kò kó lọ, nígbà tí ó kó Jehoiakini, ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu, ati gbogbo àwọn ọlọ́lá Juda ati ti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni. +OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Gbogbo àwọn ohun èlò tí ó ṣẹ́kù ní ilé rẹ, ati ní ààfin ọba Juda, ati ní Jerusalẹmu, ni +wọn óo kó lọ sí Babiloni, níbẹ̀ ni wọn yóo sì wà títí di ọjọ́ tí mo bá ranti wọn. N óo wá kó wọn pada wá sí ibí yìí nígbà náà.” +Àwọn ikọ̀ kan wá sí ọ̀dọ̀ Sedekaya, ọba Juda, ní Jerusalẹmu, láti ọ̀dọ̀ ọba Edomu ati ọba Moabu, ọba àwọn ọmọ Amoni, ọba Tire, ati ọba Sidoni wá, rán wọn pada sí àwọn oluwa wọn, +sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n sọ fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní +òun ni òun fi agbára ńlá òun dá ayé: ati eniyan ati ẹranko tí wọ́n wà lórí ilẹ̀; ẹni tí ó bá tọ́ lójú òun ni òun óo sì fi wọ́n fún. +Ó ní òun ti fún Nebukadinesari, ọba Babiloni iranṣẹ òun, ní gbogbo àwọn ilẹ̀ wọnyi, òun sì ti fún un ni àwọn ẹranko inú igbó kí wọn máa ṣe iranṣẹ rẹ̀. +Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóo máa ṣe ẹrú òun ati ọmọ rẹ̀, ati ọmọ ọmọ rẹ̀, títí àkókò tí ilẹ̀ òun pàápàá yóo fi tó, tí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba ńláńlá yóo sì kó o lẹ́rú.” +OLUWA ní, “Ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè tabi ìjọba kan bá kọ̀, tí wọn kò sin Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí wọn kò sì ti ọrùn wọn bọ àjàgà rẹ̀, ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn ni n óo fi jẹ orílẹ̀-èdè náà níyà títí n óo fi fà á lé ọba Babiloni lọ́wọ́. +Nítorí náà, ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín, ati àwọn awoṣẹ́ yín, àwọn alálàá yín ati àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, ati àwọn oṣó yín, tí wọn ń sọ fun yín pé ẹ kò ní di ẹrú ọba Babiloni. +Wolii Jeremaya ati Wolii Hananaya. +Ní ọdún kan náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda, ní oṣù karun-un ọdún kẹrin, Hananaya wolii ọmọ Aṣuri, tí ó wá láti Gibeoni bá mi sọ̀rọ̀ ní ilé OLUWA lójú àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan pé, +Hananaya wolii bá bọ́ àjàgà kúrò lọ́rùn Jeremaya, ó sì ṣẹ́ ��. +Hananaya bá sọ níṣojú gbogbo eniyan pé OLUWA ní bẹ́ẹ̀ ni òun óo ṣẹ́ àjàgà Nebukadinesari ọba Babiloni kúrò lọ́rùn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè kí ọdún meji tó pé. Wolii Jeremaya bá bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ. +Lẹ́yìn tí Hananaya wolii bọ́ àjàgà kúrò lọ́rùn Jeremaya, tí ó sì ṣẹ́ ẹ, OLUWA sọ fún Jeremaya pé, +“Lọ sọ fún Hananaya pé OLUWA ní àjàgà igi ni ó ṣẹ́, ṣugbọn àjàgà irin ni òun óo fi rọ́pò rẹ̀. +OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun ti fi àjàgà irin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè wọnyi kí wọn lè di ẹrú Nebukadinesari ọba Babiloni, kí wọn sì máa sìn ín, nítorí òun ti fi àwọn ẹranko inú igbó pàápàá fún un.” +Jeremaya wolii bá sọ fún Hananaya pé, “Tẹ́tí sílẹ̀, Hananaya, OLUWA kò rán ọ níṣẹ́, o sì ń jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gbẹ́kẹ̀lé irọ́. +Nítorí náà, OLUWA ní: òun óo mú ọ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ní ọdún yìí gan-an ni o óo sì kú, nítorí pé o ti sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ sí OLUWA.” +Ní ọdún náà gan-an ní oṣù keje, ni Hananaya wolii kú. +“OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun ti ṣẹ́ àjàgà ọba Babiloni. +Kí ó tó pé ọdún meji, òun óo kó gbogbo ohun èlò tẹmpili òun pada, tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó láti ibí yìí lọ sí Babiloni. +Òun óo mú Jehoiakini ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu, ati gbogbo àwọn tí a kó lẹ́rú láti Juda lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí, nítorí òun óo ṣẹ́ àjàgà ọba Babiloni. Ó ní OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.” +Jeremaya wolii bá dá Hananaya wolii lóhùn níṣojú àwọn alufaa ati gbogbo àwọn ará ìlú tí wọn dúró ní ilé OLUWA, +ó ní, “Amin, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀. Kí OLUWA mú àsọtẹ́lẹ̀ tí o sọ ṣẹ, kí ó kó àwọn ohun èlò ilé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan tí a kó lẹ́rú lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí. +Ṣugbọn gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ìwọ ati gbogbo àwọn eniyan wọnyi. +Àwọn wolii tí wọ́n ti wà ṣáájú èmi pẹlu rẹ ní ìgbà àtijọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ìyàn, ati àjàkálẹ̀ àrùn nípa ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati nípa àwọn ìjọba ńláńlá. +Wolii tí ó bá fẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé alaafia yóo wà, nígbà tí ọ̀rọ̀ wolii náà bá ṣẹ ni a óo mọ̀ pé OLUWA ni ó rán an níṣẹ́ nítòótọ́.” +Lẹta Jeremaya sí Àwọn Tí Ogun Kó Lọ sí Babiloni. +Jeremaya wolii kọ ìwé kan ranṣẹ láti Jerusalẹmu, ó kọ ọ́ sí àwọn àgbààgbà láàrin àwọn tí a kó ní ìgbèkùn; ati sí àwọn alufaa ati àwọn wolii, ati gbogbo àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, láti Jerusalẹmu. +“Nígbà tí aadọrin ọdún Babiloni bá pé, n óo mójú tó ọ̀rọ̀ yín, n óo mú ìlérí mi ṣẹ fun yín, n óo sì ko yín pada sí ibí yìí. +Nítorí pé mo mọ èrò tí mò ń gbà si yín, èrò alaafia ni, kì í ṣe èrò ibi. N óo mú kí ọjọ́ ọ̀la dára fun yín, n óo sì fun yín ní ìrètí. +Ẹ óo ké pè mí, ẹ óo gbadura sí mi, n óo sì gbọ́ adura yín. +Ẹ óo wá mi, ẹ óo sì rí mi, bí ẹ bá fi tọkàntọkàn wá mi. +Ẹ óo rí mi, n óo dá ire yín pada, n óo ko yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati láti gbogbo ibi tí mo ti le yín lọ; n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti le yín kúrò lọ sí ìgbèkùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Nítorí ẹ wí pé, ‘OLUWA ti gbé àwọn wolii dìde fun wa ní Babiloni.’ +Nípa ti ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú yìí, àní àwọn ará yín tí wọn kò ba yín lọ sí ìgbèkùn, +OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, n óo sì ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè jẹ ẹ́.’ +Ó ní, ‘N óo fi ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn bá wọn jà, òun óo sì sọ wọ́n di àríbẹ̀rù fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Wọn yóo di ẹni ègún, àríbẹ̀rù, àrípòṣé ati ẹni ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé wọn lọ. +Nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ tí mo rán àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, láti sọ fún wọn nígbà gbogbo. +Ṣáájú àkókò yìí, ọba Jehoiakini ati ìyá ọba ti kúrò ní Jerusalẹmu, pẹlu àwọn ìwẹ̀fà ati àwọn ìjòyè Juda ati ti Jerusalẹmu, ati àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ati àwọn oníṣẹ́-ọnà. +Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, gbogbo ẹ̀yin tí OLUWA kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.’ +“Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Jehoiakini, ati Sedekaya ọmọ Maaseaya, tí wọn ń forúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fun yín ni pé: òun óo fi wọ́n lé Nebukadinesari ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì pa wọ́n lójú yín. +Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Babiloni yóo máa fi ọ̀rọ̀ wọn ṣépè fún eniyan pé: ‘OLUWA yóo ṣe ọ́ bíi Sedekaya ati Ahabu tí ọba Babiloni sun níná,’ +nítorí pé wọ́n ti hùwà òmùgọ̀ ní Israẹli, wọ́n bá aya àwọn aládùúgbò wọn ṣe àgbèrè, wọ́n fi orúkọ òun sọ ọ̀rọ̀ èké tí òun kò fún wọn láṣẹ láti sọ. OLUWA ní òun nìkan ni òun mọ ohun tí wọ́n ṣe; òun sì ni ẹlẹ́rìí.” +OLUWA ní kí n sọ fún Ṣemaaya tí ń gbé Nehelamu pé, +“Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí ìwé tí o fi orúkọ ara rẹ kọ sí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu, ati sí Sefanaya alufaa, ọmọ Maaseaya, ati sí gbogbo àwọn alufaa, pé: +“Èmi OLUWA ti fi ìwọ Sefanaya jẹ alufaa dípò Jehoiada tí ó jẹ́ alufaa tẹ́lẹ̀ rí, ati pé mo ní kí o máa ṣe alabojuto gbogbo àwọn wèrè tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé èmi OLUWA, kí o sì máa kan ààbà mọ́ wọn ní ẹsẹ̀, kí o máa fi okùn sí wọn lọ́rùn. +Kí ló dé tí o kò bá Jeremaya ará Anatoti tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín wí. +Nítorí ó ti ranṣẹ sí wa ní Babiloni pé a á pẹ́ níbí, nítorí náà kí á kọ́lé, kí á máa gbé inú rẹ̀, kí á dá oko, kí á sì máa jẹ èso rẹ̀.” +Sefanaya Alufaa ka ìwé náà sí etí Jeremaya wolii. +Ó fi ìwé náà rán Elasa, ọmọ Ṣafani ati Gemaraya, ọmọ Hilikaya: àwọn tí Sedekaya, ọba Juda, rán lọ sọ́dọ̀ Nebukadinesari, ọba Babiloni. +OLUWA bá sọ fún Jeremaya pé, +“Ranṣẹ sí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn wí pé ohun tí OLUWA wí nípa Ṣemaaya ará Nehelamu ni pé: nítorí pé Ṣemaaya sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí òun kò rán an, ó sì mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ èké, +òun OLUWA óo fìyà jẹ Ṣemaaya ará Nehelamu náà ati ìran rẹ̀; kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo wà láàyè láàrin àwọn eniyan rẹ̀ láti fojú rí nǹkan rere tí n óo ṣe fún àwọn eniyan mi, nítorí ó ti sọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ sí OLUWA.” +Ó ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí n sọ fún gbogbo àwọn tí a ti kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni pé, +‘Ẹ máa kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé inú wọn, ẹ máa dá oko kí ẹ sì máa jẹ èso wọn. +Ẹ máa gbé iyawo kí ẹ bímọ lọkunrin ati lobinrin. Ẹ máa fẹ́ iyawo fún àwọn ọmọ yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọ yín fún ọkọ, kí wọn lè máa bímọ lọkunrin ati lobinrin. Ẹ máa pọ̀ sí i, ẹ má sì dínkù. +Ẹ máa wá alaafia ìlú tí mo ko yín lọ, ẹ máa gbadura sí OLUWA fún un, nítorí pé ninu alaafia rẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ti ní alaafia. +Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ pé kí ẹ má jẹ́ kí àwọn wolii ati àwọn tí wọn ń woṣẹ́ láàrin yín tàn yín jẹ, kí ẹ má sì fetí sí àlá tí wọn ń lá; +nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́.’ +Israẹli Alaiṣododo. +OLUWA ní, “Ṣé bí ọkọ bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀,tí iyawo náà sì kó jáde nílé ọkọ,tí ó lọ fẹ́ ẹlòmíràn,ṣé ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ lè tún lọ gbà á pada?Ṣé ilẹ̀ náà kò ní di ìbàjẹ́?Lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe àgbèrè pẹlu ọpọlọpọ olólùfẹ́;ẹ wá fẹ́ pada sọ́dọ̀ mi? +Sibẹsibẹ, lẹ́yìn gbogbo èyí, Juda arabinrin rẹ̀, ọ̀dàlẹ̀, kò fi tọkàntọkàn pada tọ̀ mí wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojú ayé ni wọ́n ń ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún mi pé, “Israẹli jẹ̀bi, aiṣootọ, ṣugbọn kò tíì tó ti Juda, ọ̀dàlẹ̀. +Lọ kéde ọ̀rọ̀ yìí sí ìhà àríwá, kí o wí pé:‘Yipada ìwọ Israẹli alaiṣootọ.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.N kò ní bínú sí ọ, nítorí aláàánú ni mí.N kò ní máa bínú lọ títí lae. +Ṣá ti gbà pé o jẹ̀bi,ati pé o ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ.O ti fi ògo rẹ wọ́lẹ̀ fún àwọn àjèjì oriṣa,lábẹ́ gbogbo igi tútù;o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ +“Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, nítorí èmi ni Oluwa yín. N óo yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín láti inú ìlú kọ̀ọ̀kan, n óo mú meji meji láti inú agbo ilé kọ̀ọ̀kan, n óo sì ko yín wá sí Sioni. +N óo fun yín ní àwọn olùṣọ́ aguntan tí ó wù mí, tí yóo fi ìmọ̀ ati òye bọ yín. +Nígbà tí ẹ bá pọ̀ síi ní ilẹ̀ náà, ẹ kò ní sọ̀rọ̀ nípa Àpótí Majẹmu OLUWA mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní sọ si yín lọ́kàn, ẹ kò ní ranti rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín kò ní fà sí i mọ́, ẹ kò sì ní ṣe òmíràn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀ +Ìtẹ́ OLUWA ni wọ́n óo máa pe Jerusalẹmu nígbà náà. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ wá sibẹ, níwájú èmi OLUWA, ní Jerusalẹmu, wọn kò ní fi oríkunkun tẹ̀ sí ìmọ̀ burúkú ọkàn wọn mọ́. +Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ará ilé Juda yóo tọ àwọn ará ilé Israẹli lọ, wọn yóo sì jọ pada láti ilẹ̀ ìhà àríwá, wọn yóo wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín tí wọ́n jogún.” +OLUWA ní,“Israẹli, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi,tí n óo sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó dára,kí n sì fún ọ ní ogún tí ó dára jù,láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù.Mo sì rò pé o óo máa pè mí ní baba rẹ,ati pé o kò ní pada kúrò lẹ́yìn mi. +Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo gbogbo òkè yíká,ibo ni ẹ kò tíì ṣe àgbèrè dé?Ẹ̀ ń dúró de olólùfẹ́ lẹ́bàá ọ̀nà,bí àwọn obinrin Arabia ninu aṣálẹ̀.Ẹ ti fi ìṣekúṣe yín ba ilẹ̀ náà jẹ́. +Dájúdájú bí obinrin alaiṣootọ tíí fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni o ti ṣe alaiṣootọ sí mi, ìwọ Israẹli.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +A gbọ́ ohùn kan lórí àwọn òkè gíga,ẹkún ati ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọkunrin Israẹli ni.Nítorí wọ́n ti yapa kúrò lójú ọ̀nà wọn;wọ́n ti gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn. +Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ,n óo mú aiṣootọ yín kúrò.“Wò wá! A wá sọ́dọ̀ rẹ,nítorí ìwọ ni OLUWA Ọlọrun wa. +Nítòótọ́, ẹ̀tàn ni àwọn òkè,ati gbogbo ohun tí wọn ń lọ ṣe níbẹ̀;dájúdájú lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa ni ìgbàlà Israẹli wà. +Ṣugbọn láti ìgbà èwe wa ni ohun ìtìjú yìíti pa gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá wa ṣiṣẹ́ fún run:ẹran ọ̀sìn wọn, ati agbo mààlúù wọn,àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin. +Ẹ jẹ́ kí á dojúbolẹ̀ kí ìtìjú wa sì bò wá,nítorí pé a ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wa;àtàwa, àtàwọn baba ńlá wa,a kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní.” +Nítorí náà ni òjò kò ṣe rọ̀,tí òjò àkọ́rọ̀ kò rọ̀ ní àkókò tí ó yẹ.Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń gbéjú gbéré bí aṣẹ́wó,ojú kò sì tì yín. +Israẹli, o wá ń pè mí nisinsinyii, ò ń sọ pé,‘Ìwọ ni baba mi, ìwọ ni ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi. +Ṣé o kò ní dáwọ́ ibinu rẹ dúró ni?Tabi títí ayé ni o óo fi máa bínú?’Lóòótọ́ o ti sọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀,ṣugbọn o ti ṣe ìwọ̀n ibi tí o lè ṣe.” +OLUWA sọ fún mi ní ìgbà ayé ọba Josaya pé: “Ṣé o rí ohun tí Israẹli, alaiṣootọ ẹ̀dá ṣe? Ṣé o rí i bí ó tí ń lọ ṣe àgbèrè lórí gbogbo òkè ati lábẹ́ gbogbo igi tútù? +Mo rò pé yóo pada tọ̀ mí wá, lẹ́yìn tí ó bá ṣe àgbèrè rẹ̀ tán ni; ṣugbọn kò pada; Juda arabinrin rẹ̀, alaiṣootọ sì rí i, +ó mọ̀ pé nítorí ìwà àgbèrè Israẹli, alaiṣootọ, ni mo ṣe lé e jáde, tí mo sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Sibẹsibẹ Juda tí òun pàápàá jẹ́ alaiṣootọ, kò bẹ̀rù, òun náà lọ ṣe àgbèrè. +Nítorí pé ìwà àgbèrè jẹ́ nǹkan kékeré lójú rẹ̀, ó ṣe àgbèrè pẹlu òkúta ati igi ó sì ba ilẹ̀ náà jẹ́. +Ìlérí OLUWA fún Àwọn Eniyan Rẹ̀. +OLUWA Ọlọrun Israẹli bá Jeremaya sọ̀rọ̀: +“Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin eniyan Jakọbu, iranṣẹ mi,ẹ má sì jẹ́ kí àyà fò yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.N óo ti òkèèrè wá gbà yín là,N óo gba àwọn ọmọ yín tí wọ́n wà ní ìgbèkùn là pẹlu.Àwọn ọmọ Jakọbu yóo pada ní ìfọ̀kànbalẹ̀ ati ìrọ̀rùn,ẹnikẹ́ni kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́. +Nítorí pé mo wà pẹlu yín, n óo gbà yín là. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n óo pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo fọn yín ká sí ni n óo parun patapata,ṣugbọn n kò ní pa ẹ̀yin run.N óo jẹ yín níyà,ṣugbọn n kò ní fi ìyà tí kò tọ́ jẹ yín.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Egbò yín kò lè san mọ́,ọgbẹ́ yín sì jinlẹ̀. +Kò sí ẹni tí yóo gba ẹjọ́ yín rò,kò ní sí òògùn fún ọgbẹ́ yín,kò ní sí ìwòsàn fun yín. +Gbogbo àwọn olólùfẹ́ yín ti gbàgbé yín;wọn kò bìkítà nípa yín mọ́,nítorí mo ti nà yín bí ọ̀tá mi,mo sì fi ìyà jẹ yín bí ọ̀tá tí kò láàánú,nítorí àṣìṣe yín pọ̀,nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ rékọjá ààlà. +Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún,nítorí ìnira yín tí kò lóògùn?Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ rékọjá ààlàni mo ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan wọnyi dé ba yín. +Ṣugbọn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ yín run, ni a óo pada jẹ run.Gbogbo àwọn ọ̀tá yín patapata, ni yóo lọ sí ìgbèkùn.Gbogbo àwọn tí wọ́n fogun kó yín ni ogun yóo kó.N óo fi ẹrù àwọn tí wọn ń jà yín lólè fún àwọn akónilẹ́rù. +N óo fun yín ní ìlera,n óo sì wo àwọn ọgbẹ́ yín sàn,èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Nítorí wọ́n ti pè yín ní ‘Ẹni ìtanù,Sioni tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún.’ ” +OLUWA ní,“Mo ṣetán láti dá ire ilé Jakọbu pada,n óo fi ojurere wo ibùgbé rẹ̀.A óo tún ìlú náà kọ́ sórí òkítì rẹ̀,a óo sì tún kọ́ ààfin rẹ̀ sí ààyè rẹ̀ tẹ́lẹ̀. +Orin ọpẹ́ yóo máa ti ibẹ̀ jáde wá,a óo sì máa gbọ́ ohùn àwọn tí ń ṣe àríyá pẹlu.N óo bukun wọn, wọn óo di pupọ,n óo sọ wọ́n di ẹni iyì, wọn kò sì ní jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ. +Ó ní, “Kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún ọ sinu ìwé, +Àwọn ọmọ wọn yóo rí bí wọn ti rí ní àtijọ́,àwọn ìjọ wọn yóo fi ìdí múlẹ̀ níwájú mi.N óo sì fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn ń ni wọ́n lára. +Ọ̀kan ninu wọn ni yóo jọba lórí wọn,ààrin wọn ni a óo sì ti yan olórí wọn;n óo fà á mọ́ra, yóo sì súnmọ́ mi,nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè fúnra rẹ̀ súnmọ́ mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Ẹ óo jẹ́ eniyan mi, n óo sì jẹ́ Ọlọrun yín.” +Ẹ wo ìjì OLUWA!Ibinu rẹ̀ ń bọ̀ bí ìjì líle.Ó ń bọ̀ sórí àwọn oníṣẹ́ ibi. +Ibinu gbígbóná OLUWA kò ní yipada,títí yóo fi mú èrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ.Òye nǹkan wọnyi yóo ye yín ní ọjọ́ ìkẹyìn. +nítorí pé àkókò ń bọ̀ tí n óo dá ire àwọn eniyan mi, Israẹli ati Juda pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo mú wọn pada wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn, yóo sì di ohun ìní wọn.” +Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ nípa Israẹli ati Juda nìyí: +“A ti gbọ́ igbe ìdágìrì ati ti ẹ̀rù,kò sì sí alaafia. +Ẹ bèèrè, kí ẹ sì ṣe ìwádìí;ǹjẹ́ ọkunrin lè lóyún kí ó sì bímọ?Kí ló wá dé tí mo rí gbogbo ọkunrin,tí wọn ń dáwọ́ tẹ ìbàdí bí obinrin tí ń rọbí?Kí ló dé tí gbogbo yín fajúro? +Ọjọ́ ńlá lọjọ́ náà yóo jẹ́,kò sí ọjọ́ tí yóo dàbí rẹ̀,àkókò ìpọ́njú ni yóo jẹ́ fún ilé Jakọbu;ṣugbọn wọn yóo bọ́ ninu rẹ̀.” +OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá,n óo já àjàgà kúrò lọ́rùn wọn.N óo já ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi so wọ́n,wọn kò sì ní ṣe iranṣẹ fún àjèjì mọ́. +Ṣugbọn wọn yóo máa sin Ọlọrun wọn,ati ti Dafidi, ọba wọn, tí n óo gbé dìde fún wọn. +Israẹli Pada sílé. +OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ Ọlọrun gbogbo ìdílé Israẹli,tí àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi. +OLUWA ní, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ èmi OLUWA, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,kí ẹ sì kéde rẹ̀ ní èbúté lókèèrè réré;ẹ sọ pé, ‘Ẹni tí ó fọ́n Israẹli ká ni yóo kó wọn jọ,yóo sì máa tọ́jú wọn, bí olùṣọ́-aguntan tíí tọ́jú agbo aguntan rẹ̀.’ +Nítorí OLUWA yóo ra ilé Jakọbu pada,yóo rà wọ́n pada lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára jù wọ́n lọ. +Wọn yóo wá kọrin lórí òkè Sioni,wọn óo sì yọ̀ lórí nǹkan ọ̀pọ̀ oore tí OLUWA yóo ṣe fún wọn:Wọ́n óo yọ̀ nítorí oore ọkà ati waini ati òróró,ati aguntan ati ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù;ayé wọn óo dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, wọn kò ní dààmú mọ́. +Àwọn ọdọmọbinrin óo máa jó ijó ayọ̀ nígbà náà,àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn àgbààgbà, yóo sì máa ṣe àríyá.N óo sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,n óo tù wọ́n ninu, n óo sì fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́ wọn. +N óo fún àwọn alufaa ní ọpọlọpọ oúnjẹ,n óo sì fi oore mi tẹ́ àwọn eniyan mi lọ́rùn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA ní,“A gbọ́ ohùn kan ní Rama,ariwo ẹkún ẹ̀dùn ati arò ni.Rakẹli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀,wọ́n ṣìpẹ̀ fún un títí, kò gbà,nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́. +Má sọkún mọ́, nu ojú rẹ nù,nítorí o óo jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.Àwọn ọmọ rẹ yóo pada wá láti ilẹ̀ ọ̀tá wọn. +Ìrètí ń bẹ fún ọ lẹ́yìn ọ̀la,àwọn ọmọ rẹ yóo pada sí orílẹ̀-èdè wọn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Mo gbọ́ bí Efuraimu tí ń kẹ́dùn,ó ní: ‘O ti bá mi wí, ìbáwí sì dùn mí,bí ọmọ mààlúù tí a kò kọ́.Mú mi pada, kí n lè pada sí ààyè mi,nítorí pé ìwọ ni OLUWA, Ọlọrun mi. +Nítorí pé lẹ́yìn tí mo ṣáko lọ, mo ronupiwada;lẹ́yìn tí o kọ́ mi lọ́gbọ́n, ń ṣe ni mo káwọ́ lérí.Ojú tì mí, ìdààmú sì bá mi,nítorí ìtìjú ohun tí mo ṣe nígbà èwe mi dé bá mi.’ +Àwọn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà, rí àánú OLUWA ninu aṣálẹ̀;nígbà tí Israẹli ń wá ìsinmi, +“Ṣé ọmọ mi ọ̀wọ́n ni Efuraimu ni?Ṣé ọmọ mi àtàtà ni?Nítorí bí mo tí ń sọ̀rọ̀ ibinu sí i tó, sibẹ mò ń ranti rẹ̀,nítorí náà ọkàn rẹ̀ ń fà mí;dájúdájú n óo ṣàánú rẹ̀. +Ẹ ri òpó mọ́lẹ̀ lọ fún ara yín,ẹ sàmì sí àwọn ojú ọ̀nà.Ẹ wo òpópónà dáradára, ẹ fiy��sí ọ̀nà tí ẹ gbà lọ.Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ Israẹli,ẹ pada sí àwọn ìlú yín wọnyi. +Ìgbà wo ni ẹ óo ṣe iyèméjì dà, ẹ̀yin alainigbagbọ wọnyi?Nítorí OLUWA ti dá ohun titun sórí ilẹ̀ ayé,bíi kí obinrin máa dáàbò bo ọkunrin.” +OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọn yóo tún máa lo gbolohun yìí ní ilẹ̀ Juda ati ní àwọn ìlú rẹ̀, nígbà tí mo bá dá ire wọn pada, wọn óo máa wí pé,‘OLUWA yóo bukun ọ, ìwọ òkè mímọ́ Jerusalẹmu,ibùgbé olódodo.’ +Àwọn eniyan yóo máa gbé àwọn ìlú Juda ati àwọn agbègbè rẹ̀ pẹlu àwọn àgbẹ̀ ati àwọn darandaran. +Nítorí pé n óo fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní agbára; n óo sì tu gbogbo ọkàn tí ń kérora lára.” +Lẹ́sẹ̀ kan náà mo tají, mo wò yíká, oorun tí mo sùn sì dùn mọ́ mi. +OLUWA ní, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo kó àtènìyàn, àtẹranko kún ilẹ̀ Israẹli ati ilẹ̀ Juda. +Nígbà tí àkókò bá tó, gẹ́gẹ́ bí mo tí ń ṣọ́ wọn tí mo fi fà wọ́n tu, tí mo wó wọn lulẹ̀, tí mo bì wọ́n wó, tí mo pa wọ́n run, tí mo sì mú kí ibi ó bá wọn; bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣọ́ wọn tí n óo fi kọ́ àwọn ìlú wọn tí n óo sì fìdí wọn múlẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Tó bá dìgbà náà, àwọn eniyan kò ní máa wí mọ́ pé,‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà kíkan,àwọn ọmọ wọn ni eyín kan.’ +OLUWA yọ sí wọn láti òkèèrè.Ìfẹ́ àìlópin ni mo ní sí ọ,nítorí náà n kò ní yé máa fi òtítọ́ bá ọ lò. +Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó bá jẹ èso àjàrà kíkan,òun ni eyín yóo kan.Olukuluku ni yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀. +“Ọjọ́ ń bọ̀, tí ń óo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun. +Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, ní ìgbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde ní ilẹ̀ Ijipti, àní majẹmu mi tí wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ọkọ wọn. +Ṣugbọn majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tó bá yá nìyí: N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn. N óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì máa jẹ́ eniyan mi. +Ẹnikẹ́ni kò ní máa kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀ bí a ti í mọ èmi OLUWA mọ́, gbogbo wọn ni wọn yóo mọ̀ mí ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki. N óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n kò sì ní ranti àìdára wọn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA ni ó dá oòrùn, láti máa ràn ní ọ̀sán,tí ó fún òṣùpá ati ìràwọ̀ láṣẹ, láti tan ìmọ́lẹ̀ lálẹ́,tí ó rú omi òkun sókè, tí ìgbì rẹ̀ ń hó yaya,òun ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun. +Òun ló sọ pé, àfi bí àwọn àṣẹ wọnyi bá yipada níwájú òun,ni àwọn ọmọ Israẹli kò fi ní máa jẹ́ orílẹ̀-èdè títí lae. +Àfi bí eniyan bá lè wọn ojú ọ̀run,tí ó sì lè wádìí ìpìlẹ̀ ayé,ni òun lè ké àwọn ọmọ Israẹli kúrò,nítorí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe. +OLUWA ni, “Ẹ wò ó! Àkókò ń bọ̀ tí a óo tún Jerusalẹmu kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli títí dé Bodè Igun. +A óo ta okùn ìwọ̀n odi ìlú títí dé òkè Garebu, ati títí dé Goa pẹlu. +N óo tún yín gbé dìde, ẹ óo sì di ọ̀tun, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.Ẹ óo tún fi aro lu ìlù ayọ̀, ẹ óo sì jó ijó ìdùnnú. +Gbogbo àfonífojì tí wọn ń da òkú ati eérú sí, ati gbogbo pápá títí dé odò Kidironi, dé ìkangun Bodè Ẹṣin, ní ìhà ìlà oòrùn, ni yóo jẹ́ ibi mímọ́ fún OLUWA. Wọn kò ní fọ́ ọ mọ́, ẹnìkan kò sì ní wó o lulẹ̀ títí laelae.” +Ẹ óo tún ṣe ọgbà àjàrà sórí òkè Samaria;àwọn tí wọ́n gbin àjàrà ni yóo sì gbádùn èso orí rẹ̀. +Nítorí pé ọjọ́ kan ń bọ̀, tí àwọn aṣọ́nà yóo pè yín láti orí òkè Efuraimu pé,‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ sí òkè Sioni,sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa.’ ” +OLUWA ní,“Ẹ kọ orin sókè pẹlu ìdùnnú fún Jakọbu,kí ẹ sì hó fún olórí àwọn orílẹ̀-èdè,ẹ kéde, ẹ kọ orin ìyìn, kí ẹ sì wí pé,‘OLUWA ti gba àwọn eniyan rẹ̀ lààní, àwọn eniyan Israẹli yòókù.’ +Ẹ wò ó! N óo kó wọn wá láti ilẹ̀ àríwá,n óo kó wọn jọ láti òpin ayé.Àwọn afọ́jú ati arọ yóo wà láàrin wọn,ati aboyún ati àwọn tí wọn ń rọbí lọ́wọ́.Ogunlọ́gọ̀ eniyan ni àwọn tí yóo pada wá síbí. +Tẹkúntẹkún ni wọn yóo wá,tàánútàánú ni n óo sì fi darí wọn pada.N óo mú kí wọn rìn ní etí odò tí ń ṣàn,lójú ọ̀nà tààrà, níbi tí wọn kò ti ní fẹsẹ̀ kọ;nítorí pé baba ni mo jẹ́ fún Israẹli, àkọ́bí mi sì ni Efuraimu.” +Jeremaya Ra Ilẹ̀. +OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní ọdún kẹwaa tí Sedekaya jọba ní Juda, tí ó jẹ́ ọdún kejidinlogun tí Nebukadinesari jọba. +Mo kọ ọ́ sinu ìwé, mo fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́, mo pe àwọn eniyan láti ṣe ẹlẹ́rìí; mo sì fi òṣùnwọ̀n wọn fadaka náà. +Mo mú ìwé ilẹ̀ náà tí a ti fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ati ẹ̀dà rẹ̀, +mo sì fún Baruku ọmọ Neraya ọmọ Mahiseaya ní èyí tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀, níṣojú Hanameli, ọmọ arakunrin baba mi ati níṣojú àwọn ẹlẹ́rìí tí wọn fọwọ́ sí ìwé ilẹ̀ náà, ati níṣojú gbogbo àwọn ará Juda tí wọn jókòó ní àgbàlá àwọn olùṣọ́ náà. +Mo pàṣẹ fún Baruku níṣojú wọn pé, +‘OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí o mú ìwé ilẹ̀ yìí, ati èyí tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀ tí a sì ká, ati ẹ̀dà rẹ̀, kí o fi wọ́n sinu ìkòkò amọ̀ kí wọ́n lè wà níbẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́. +Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ pé: wọn yóo tún máa ra ilẹ̀ ati oko ati ọgbà àjàrà ní ilẹ̀ yìí.’ +“Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé ilẹ̀ náà lé Baruku ọmọ Neraya lọ́wọ́, mo gbadura sí OLUWA, mo ní: +‘OLUWA, Ọlọrun! Ìwọ tí o dá ọ̀run ati ayé pẹlu agbára ńlá ati ipá rẹ! Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ, +ìwọ tí ò ń fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, ṣugbọn tí ò ń gba ẹ̀san àwọn baba lára àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn ikú wọn, ìwọ Ọlọrun alágbára ńlá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, +ìwọ Olùdámọ̀ràn ńlá, tí ó lágbára ní ìṣe; ìwọ tí ojú rẹ ń rí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ eniyan, tí o sì ń san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀; +Àwọn ọmọ ogun Babiloni dó ti Jerusalẹmu ní àkókò yìí, Jeremaya wolii sì wà ní ẹ̀wọ̀n tí wọ́n sọ ọ́ sí, ní àgbàlá ààfin ọba Juda. +ìwọ tí o ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Ijipti, o sì tún ń ṣe iṣẹ́ náà títí di òní ní Israẹli ati láàrin gbogbo eniyan; o sì ti fìdí orúkọ rẹ múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí. +Ìwọ ni o kó àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan rẹ, jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu, pẹlu ọwọ́ agbára, ipá ati ìbẹ̀rù ńlá. +O sì fún wọn ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí o búra fún àwọn baba ńlá wọn pé o óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin. +Wọ́n dé ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á; ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, wọn kò sì pa òfin rẹ mọ́. Wọn kò ṣe ọ̀kan kan ninu gbogbo ohun tí o pàṣẹ fún wọn láti máa ṣe; nítorí náà ni o ṣe mú kí gbogbo ibi tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn bá wọn! +“ ‘Wo bí àwọn ọ̀tá ti mọ òkítì sí ara odi wa láti gba ìlú wa. Nítorí ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, a óo fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì í lọ́wọ́. Ohun tí o wí ṣẹ, o sì ti rí i. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, sibẹsibẹ, ìwọ OLUWA Ọlọrun ni o sọ fún mi pé kí n ra ilẹ̀, kí n sì ní àwọn ẹlẹ́rìí.’ ” +OLUWA sọ fún Jeremaya pé, +“Wò ó! Èmi ni OLUWA, Ọlọrun gbogbo eniyan, ǹjẹ́ nǹkankan wà tí ó ṣòro fún mi láti ṣe? +Nítorí náà èmi OLUWA ni mo sọ pé, n óo fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea ati Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì gbà á. +Àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun ti ìlú yìí, yóo wọ inú rẹ̀, wọn yóo sì dáná sun ún pẹlu àwọn ilẹ̀ tí wọ́n tí ń sun turari sí oriṣa Baali lórí wọn, tí wọ́n sì tí ń rú ẹbọ ohun mímu sí àwọn oriṣa tí wọn ń mú mi bínú. +Sedekaya ọba Juda ni ó sọ Jeremaya sẹ́wọ̀n, ó ní, kí ló dé tí Jeremaya fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé OLUWA ní òun óo fi Jerusalẹmu lé ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì gbà á; +Nítorí láti ìgbà èwe àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn eniyan Juda ni wọ́n tí ń ṣe kìkì nǹkan tí ó burú lójú mi, kìkì nǹkan tí yóo bí mi ninu ni àwọn ọmọ Israẹli náà sì ń ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Láti ọjọ́ tí wọn ti tẹ ìlú yìí dó títí di òní, ni àwọn ará ilẹ̀ yìí tí ń mú mi bínú, tí wọn sì ń mú kí inú mi ó máa ru, kí n lè pa wọ́n rẹ́ kúrò níwájú mi, +nítorí gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará ilẹ̀ Juda ṣe láti mú mi bínú, àtàwọn ọba wọn, àtàwọn ìjòyè wọn, àtàwọn alufaa wọn, àtàwọn wolii wọn; àtàwọn ará Juda àtàwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. +Wọ́n ti yíjú kúrò lọ́dọ̀ mi, wọ́n sì kẹ̀yìn sí mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti kọ́ wọn ni àkọ́túnkọ́, wọn kò gba ẹ̀kọ́. +Wọ́n gbé àwọn ère wọn, tí ó jẹ́ ohun ìríra fun mi sinu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, kí wọ́n lè sọ ọ́ di ibi àìmọ́. +Wọ́n kọ́ ojúbọ oriṣa tí ó wà ní àfonífojì ọmọ Hinomu láti máa fi àwọn ọmọ wọn, lọkunrin ati lobinrin rú ẹbọ sí oriṣa Moleki, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò pa á láṣẹ fún wọn, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn pé wọ́n lè ṣe irú ohun ìríra bẹ́ẹ̀, láti mú Juda dẹ́ṣẹ̀.” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún mi pé, “Ìlú tí àwọn eniyan ń sọ pé ọwọ́ ọba Babiloni ti tẹ̀, nítorí ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, +n óo kó àwọn eniyan ibẹ̀ jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti fi ibinu, ìrúnú, ati ìkanra lé wọn lọ; n óo kó wọn pada sí ibí yìí, n óo sì mú kí wọn máa gbé ní àìléwu. +Wọn yóo máa jẹ́ eniyan mi, Èmi náà óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn. +N óo fún wọn ní ọkàn ati ẹ̀mí kan, kí wọn lè máa bẹ̀rù mi nígbà gbogbo, kí ó lè dára fún àwọn ati àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn wọn. +ati pé Sedekaya ọba Juda kò ní bọ́ lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea. Ó ní Jeremaya sọ pé dájúdájú, OLUWA óo fi òun Sedekaya lé ọba Babiloni lọ́wọ́, àwọn yóo rí ara àwọn lojukooju, àwọn yóo sì bá ara àwọn sọ̀rọ̀. +N óo bá wọn dá majẹmu ayérayé, pé n kò ní dẹ́kun ati máa ṣe wọ́n lóore. N óo fi ẹ̀rù mi sí wọn lọ́kàn, kí wọn má baà yapa kúrò lọ́dọ̀ mi mọ́. +Yóo máa jẹ́ ohun ayọ̀ fún mi láti ṣe wọ́n lóore, n óo fi tẹ̀mítẹ̀mí ati tọkàntọkàn fi ìdí wọn múlẹ̀ ninu jíjẹ́ olóòótọ́ ní ilẹ̀ yìí. +“Bí mo ṣe mú gbogbo ibi ńlá yìí bá àwọn eniyan wọnyi, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe mú kí gbogbo ohun rere tí mo ti ṣe ìlérí fún wọn dé bá wọn. +Wọn yóo ra oko ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọ pé ó ti di ahoro, tí kò sí eniyan tabi ẹranko ninu rẹ̀, tí ẹ̀ ń sọ pé a ti fi lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́. +Wọn yóo máa fi owó ra oko, wọn yóo máa ṣe ìwé ilẹ̀, wọn yóo máa fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́; wọn yóo máa fi èdìdì dì í, àwọn ẹlẹ́rìí yóo sì máa fi ọwọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa rí ní ilẹ̀ Bẹnjamini. Nígbà tí mo bá dá ire wọn pada, ati ní àwọn agbègbè Jerusalẹmu, ní àwọn ìlú Juda, ati àwọn ìlú agbègbè olókè, ní àwọn ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela, ati àwọn ìlú ilẹ̀ Nẹgẹbu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Yóo mú òun Sedekaya lọ sí Babiloni, ibẹ̀ ni òun óo sì wà títí OLUWA yóo fi ṣe ẹ̀tọ́ fún òun. Ó ní bí àwọn tilẹ̀ bá àwọn ará Kalidea jagun, àwọn kò ní borí. +Jeremaya ní, “OLUWA sọ fún mi pé, +‘Hanameli ọmọ Ṣalumu, arakunrin baba rẹ, yóo wá bá ọ pé kí o ra oko òun tí ó wà ní Anatoti, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada.’ +Lẹ́yìn náà Hanameli ọmọ arakunrin baba mi tọ̀ mí wá sí àgbàlá àwọn olùṣọ́ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, ó sì wí fún mi pé, ‘Jọ̀wọ́ ra oko mi tí ó wà ní Anatoti ní ilẹ̀ Bẹnjamini, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada; rà á fún ara rẹ.’“Nígbà náà ni mo wá mọ̀ pé àṣẹ OLUWA ni. +Mo bá ra oko náà lọ́wọ́ Hanameli ọmọ arakunrin baba mi, mo sì wọn fadaka ṣekeli mẹtadinlogun fún un. +Ìlérí Ìrètí Mìíràn. +OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹẹkeji, nígbà tí ó ṣì wà ní ẹ̀wọ̀n, ní àgbàlá àwọn tí ń ṣọ́ ààfin. +OLUWA ní, “A óo tún gbọ́ ohùn ayọ̀ ati inú dídùn ninu ìlú Juda ati ìgboro Jerusalẹmu, tí ẹ sọ wí pé ó ti di ahoro, tí kò sí eniyan tabi ẹranko tó ń gbé inú wọn. +A óo tún gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo ati ohùn àwọn tí wọn ń kọrin bí wọ́n ti ń mú ẹbọ ọpẹ́ wá sinu ilé OLUWA wí pé: 107:1; 118:1; 136:1‘Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun,nítorí pé rere ni OLUWA,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae!’Nítorí pé n óo dá ire wọn pada bíi ti ìgbà àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ pé, “Ní gbogbo ibi tí ó ti di ahoro yìí, tí eniyan tabi ẹranko kò gbé ibẹ̀, àwọn olùṣọ́-aguntan yóo sì tún máa tọ́jú àwọn agbo ẹran wọn ninu gbogbo àwọn ìlú ibẹ̀. +Àwọn agbo ẹran yóo tún kọjá níwájú ẹni tí ó ń kà wọ́n ninu àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè olókè, ati àwọn ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela ati àwọn ìlú tí wọn wà ní Nẹgẹbu, ní ilẹ̀ Bẹnjamini, ní agbègbè tí ó yí Jerusalẹmu ká, ati àwọn ìlú Juda. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Ó ní, “Àkókò ń bọ̀, tí n óo mú ìlérí tí mo ṣe fún ilé Israẹli ati ilé Juda ṣẹ. +Nígbà tó bá yá, tí àkókò bá tó, n óo mú kí ẹ̀ka òdodo kan ó sọ jáde ní ilé Dafidi, yóo máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati ti òdodo ní ilẹ̀ náà. +A óo gba Juda là, Jerusalẹmu yóo sì wà ní àìléwu, orúkọ tí a óo wá máa pè é ni ‘OLÚWA ni Òdodo wa.’ ” +Nítorí OLUWA ní kò ní sí ìgbà kan, tí kò ní jẹ́ pé ọkunrin kan ní ilé Dafidi ni yóo máa jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli, +bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní sí ìgbà kan tí ẹnìkan ninu àwọn alufaa, ọmọ Lefi, kò ní máa dúró níwájú òun láti rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, láti máa rú ẹbọ títí lae. +OLUWA tún bá Jeremaya sọ̀rọ̀; +OLUWA tí ó dá ayé, tí ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA, ni ó sọ pé: +ó ní, “Bí ẹ bá lè ba majẹmu tí mo bá ọ̀sán ati òru dá jẹ́, tí wọn kò fi ní wà ní àkókò tí mo yàn fún wọn mọ́, +òun nìkan ni majẹmu tí mo bá Dafidi iranṣẹ mi dá ṣe lè yẹ̀, tí ìdílé rẹ̀ kò fi ní máa ní ọmọkunrin kan tí yóo jọba; bẹ́ẹ̀ náà ni majẹmu tí mo bá àwọn alufaa, ọmọ Lefi iranṣẹ mi dá. +Bí a kò ti ṣe lè ka iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí a kò sì lè wọn yanrìn etí òkun, bẹ́ẹ̀ ní n óo ṣe sọ arọmọdọmọ Dafidi ati arọmọdọmọ Lefi alufaa, iranṣẹ mi, di pupọ.” +OLUWA bi Jeremaya pé: +“Ṣé o kò gbọ́ ohun tí àwọn eniyan wọnyi ń sọ tí wọn ní, ‘OLUWA ti kọ ìdílé mejeeji tí ó yàn sílẹ̀?’ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń fojú tẹmbẹlu àwọn eniyan mi, títí tí wọn kò fi dàbí orílẹ̀-èdè lójú wọn mọ́. +Bí n kò bá tíì fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu ọ̀sán ati òru, tí n kò sì ṣe ìlànà fún ọ̀run ati ayé, +òun nìkan ni n óo fi kọ arọmọdọmọ Jakọbu ati Dafidi, iranṣẹ mi sílẹ̀, tí n kò fi ní máa yan ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ láti jọba lórí ìran Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu. N óo dá ire wọn pada, n óo sì ṣàánú fún wọn.” +“Ẹ ké pè mí, n óo sì da yín lóhùn; n óo sọ nǹkan ìjìnlẹ̀ ati ìyanu ńlá, tí ẹ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ fun yín.” +OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn ilé tí wọ́n wà ní ìlú yìí, ati ilé ọba Juda, àwọn tí wọn dótì wá, tí wọn ń gbógun tì wá yóo wó wọn lulẹ̀ +Ó ní, “Àwọn ará Kalidea ń gbógun bọ̀, wọn yóo da òkú àwọn eniyan tí n óo fi ibinu ati ìrúnú pa kún àwọn ilé tí ó wà ní ìlú yìí, nítorí mo ti fi ara pamọ́ fún ìlú yìí nítorí gbogbo ìwà burúkú wọn. +N óo mú ìlera ati ìwòsàn wá bá wọn; n óo wò wọ́n sàn, n óo sì fún wọn ní ọpọlọpọ ibukun ati ìfọ̀kànbalẹ̀. +N óo dá ire Juda ati ti Israẹli pada, n óo sì tún wọn kọ́, wọn yóo dàbí wọ́n ti rí lákọ̀ọ́kọ́. +N óo wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sí mi, n óo dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati oríkunkun tí wọ́n ṣe sí mi jì wọ́n. +Orúkọ ìlú yìí yóo sì jẹ́ orúkọ ayọ̀ fún mi, yóo jẹ́ ohun ìyìn ati ògo níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé tí yóo gbọ́ nípa nǹkan rere tí n óo ṣe fún wọn; ẹ̀rù yóo bà wọ́n, wọn yóo sì wárìrì, nítorí gbogbo nǹkan rere tí n óo máa ṣe fún ìlú náà.” +Iṣẹ́ tí A Rán sí Sedekaya. +Ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá Jeremaya sọ nìyí, nígbà tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati gbogbo ìjọba ayé tí wọ́n wà lábẹ́ rẹ̀, ati gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbógun ti Jerusalẹmu ati gbogbo àwọn ìlú Juda. +Gbogbo àwọn ìjòyè ati àwọn ará ìlú tí wọ́n dá majẹmu yìí ni wọ́n gbọ́ràn, tí wọ́n sì dá àwọn ẹrú wọn lọkunrin ati lobinrin sílẹ̀; wọn kò sì fi wọ́n ṣe ẹrú mọ́. +Ṣugbọn nígbà tó yá, wọ́n yí ọ̀rọ̀ pada, wọ́n tún mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, wọ́n tún fi ipá sọ wọ́n di ẹrú. +OLUWA wá sọ fún Jeremaya pé, +“Èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli bá àwọn baba ńlá yín dá majẹmu nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò lóko ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti, mo ní, +lẹ́yìn ọdún meje, kí olukuluku yín máa dá ọmọ Heberu tí ó bá fi owó rà lẹ́rú sílẹ̀, lẹ́yìn tí ó bá ti sin oluwa rẹ̀ fún ọdún mẹfa. Mo ní ẹ gbọdọ̀ dá ẹrú náà sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ ní òmìnira, ṣugbọn àwọn baba ńlá yín kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. +Láìpẹ́ yìí, ẹ ronupiwada, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi; ẹ kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn arakunrin yín. Ẹ dá majẹmu níwájú mi ninu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè. +Ṣugbọn ẹ tún yí ọ̀rọ̀ pada, ẹ ba orúkọ mi jẹ́ nípa pé olukuluku yín, ẹ tún mú ẹrukunrin ati ẹrubinrin tí ẹ dá sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn yín, ẹ sì tún sọ wọ́n di ẹrú pada. +Nítorí náà ẹ kò gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu pé kí olukuluku kéde òmìnira fún arakunrin rẹ̀ ati ọmọnikeji rẹ̀. Ẹ wò ó! N óo kéde òmìnira fun yín: òmìnira sí ọwọ́ ogun, àjàkálẹ̀ àrùn ati ìyàn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo sì fi yín ṣe ẹrú fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. +Àwọn ọkunrin tí wọn bá rú òfin mi, tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà majẹmu tí wọn dá níwájú mi, n óo bẹ́ wọn bíi ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí wọn bẹ́ sí meji, tí wọ́n sì gba ààrin rẹ̀ kọjá. +Bí àwọn ìjòyè Juda ati àwọn ìjòyè Jerusalẹmu, àwọn ìwẹ̀fà, àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà ṣe bẹ́ ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù sí meji, tí wọn sì gba ààrin rẹ̀ kọjá láti bá mi dá majẹmu, ni n óo ṣe bẹ́ àwọn náà. +OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, kí n lọ sọ fún Sedekaya, ọba Juda pé òun OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ìlú yìí lé ọba Babiloni lọ́wọ́; yóo sì dáná sun ún. +N óo fà wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn; òkú wọn yóo di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko. +N óo fi Sedekaya, ọba Juda ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn. Wọn óo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni tí ó ti ṣígun kúrò lọ́dọ̀ wọn. +Ẹ wò ó, n óo pàṣẹ, n óo sì kó wọn pada sí ìlú yìí, wọn yóo gbógun tì í, wọn yóo gbà á; wọn yóo sì dáná sun ún. N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro, kò ní sí eniyan tí yóo máa gbé inú wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Sedekaya, o kò ní sá àsálà, ṣugbọn wọn óo mú ọ, wọn óo fà ọ́ lé Nebukadinesari lọ́wọ́, ẹ óo rí ara yín lojukooju, ẹ óo bá ara yín sọ̀rọ̀, o óo sì lọ sí Babiloni. +Sibẹsibẹ, ìwọ Sedekaya, ọba Juda OLUWA ní wọn kò ní fi idà pa ọ́. +O óo fi ọwọ́ rọrí kú ni. Bí wọn ti sun turari níbi òkú àwọn baba rẹ, ati níbi òkú àwọn ọba tí wọ́n ti kú ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo sun turari níbi òkú ìwọ náà. Wọn yóo dárò rẹ, wọn yóo máa wí pé, ‘Ó ṣe, oluwa mi,’ nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA ṣe ìlérí; èmi ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Jeremaya wolii bá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún Sedekaya ọba Juda, ní Jerusalẹmu, +ní àkókò tí àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni gbógun ti Jerusalẹmu ati Lakiṣi ati Aseka, nítorí pé àwọn nìkan ni wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn ìlú olódi Juda. +OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí Sedekaya ọba ti bá gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu dá majẹmu pé kí wọn kéde ìdásílẹ̀, +kí olukuluku dá ẹrú rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, tí wọ́n jẹ́ Heberu sílẹ̀, kí wọn máa lọ ní òmìnira; kí ẹnikẹ́ni má sì fi Juu arakunrin rẹ̀ ṣe ẹrú mọ́. +Jeremaya ati Àwọn Ọmọ Rekabu. +OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní ìgbà ayé Jehoiakimu ọmọ Josaya, ọba Juda; ó ní, +Inú àgọ́ ni à ń gbé, a sì pa gbogbo àṣẹ tí Jonadabu baba ńlá wa fún wa mọ́. +Ṣugbọn nígbà tí Nebukadinesari, ọba Babiloni gbógun ti ilẹ̀ yìí, a wí fún ara wa pé kí á wá sí Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù àwọn ọmọ ogun, àwọn ará Kalidea ati ti àwọn ará Siria. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe di ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu.” +OLUWA bá sọ fún Jeremaya pé, +“Èmi OLUWA, àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí o lọ sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu pé, ṣé wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ kí wọn sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi ni? +Àwọn ọmọ Rekabu pa òfin tí Jonadabu, baba ńlá wọn, fún wọn mọ́, pé kí wọn má mu ọtí waini, wọn kò sì mu ọtí rárá títí di òní olónìí, nítorí pé wọ́n pa àṣẹ baba ńlá wọn mọ́. Mo ti bá yín sọ̀rọ̀ ní ọpọlọpọ ìgbà, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. +Mo ti rán gbogbo àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, si yín, ní ọpọlọpọ ìgbà pé kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú tí ó ń tọ̀, kí ẹ tún ìwà yín ṣe, kí ẹ má sá tẹ̀lé àwọn oriṣa kiri, kí ẹ yé máa sìn wọ́n; kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Ṣugbọn ẹ kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. +Àwọn ọmọ Jonadabu, ọmọ Rekabu mú àṣẹ baba ńlá wọn tí ó pa fún wọn ṣẹ, ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. +Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ́ kí ibi bá àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, nítorí pé mo bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kò gbọ́; mo pè wọ́n, wọn kò dáhùn.” +Ṣugbọn Jeremaya sọ fún àwọn ọmọ Rekabu pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Nítorí pé ẹ gbọ́ràn sí Jonadabu baba ńlá yín lẹ́nu, ẹ sì pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́, ẹ sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ pé kí ẹ máa ṣe, +nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní títí lae, kò ní sí ìgbà kan tí Jonadabu, ọmọ Rekabu kò ní ní ẹnìkan tí yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú mi.’ ” +“Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu kí o bá wọn sọ̀rọ̀, mú wọn wá sinu ọ̀kan ninu àwọn yàrá tí ó wà ninu ilé OLUWA, kí o sì fi ọtí lọ̀ wọ́n.” +Mo bá mú Jaasanaya ọmọ Jeremaya ọmọ Habasinaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo ìdílé Rekabu, +mo mú wọn wá sinu ilé OLUWA. Mo kó wọn lọ sinu yàrá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hanani, ọmọ Igidalaya eniyan Ọlọrun, yàrá náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ yàrá àwọn ìjòyè, lókè yàrá Maaseaya ọmọ Ṣalumu, aṣọ́nà. +Mo gbé ìgò ọtí kalẹ̀ níwájú àwọn ọmọ Rekabu, mo kó ife tì í. Mo bá sọ fún wọn pé, “Ó yá, ẹ máa mu ọtí waini.” +Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “A kò ní mu ọtí kankan nítorí pé Jonadabu, baba ńlá wa tíí ṣe ọmọ Rekabu ti pàṣẹ fún wa pé a kò gbọdọ̀ mu ọtí, ati àwa ati arọmọdọmọ wa títí lae. +A kò gbọdọ̀ kọ́ ilé, a kò gbọdọ̀ dá oko, a kò gbọdọ̀ gbin ọgbà àjàrà. Ó ní inú àgọ́ ni kí á máa gbé ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, kí ọjọ́ wa baà lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí à ń gbé. +A gbọ́ràn sí Jonadabu baba ńlá wa lẹ́nu, à ń pa gbogbo àṣẹ tí ó pa fún wa mọ́, pé kí á má mu ọtí ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, àwa, àwọn aya wa ati àwọn ọmọ wa lọkunrin ati lobinrin. +Ó ní a kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tí a óo máa gbé. A kò ṣe ọgbà àjàrà, tabi kí á dá oko, tabi kí á gbin ohun ọ̀gbìn. +Baruku Ka Àkọsílẹ̀ ninu Ilé OLUWA. +Ní ọdún kẹrin ìjọba Jehoiakimu ọmọ Josaya ọba Juda, OLUWA sọ fún Jeremaya pé, +Baruku bá ka ọ̀rọ̀ Jeremaya tí ó kọ sinu ìwé, sí etígbọ̀ọ́ gbogbo eniyan ní yàrá Gemaraya, ọmọ Ṣafani, akọ̀wé, tí ó wà ní gbọ̀ngàn òkè ní Ẹnu Ọ̀nà Titun ilé OLUWA. +Nígbà tí Mikaaya ọmọ Gemaraya, ọmọ Ṣafani gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA tí ó wà ninu ìwé náà; +Ó lọ sí yàrá akọ̀wé ní ààfin ọba, ó bá gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn jókòó níbẹ̀: Eliṣama akọ̀wé ati Delaaya ọmọ Ṣemaaya, ati Elinatani ọmọ Akibori, ati Gemaraya ọmọ Ṣafani, ati Sedekaya ọmọ Hananaya ati gbogbo àwọn ìjòyè. +Mikaaya sọ gbogbo ohun tí ó gbọ́, nígbà tí Baruku ka ohun tí ó kọ sinu ìwé fún wọn. +Gbogbo àwọn ìjòyè bá rán Jehudi ọmọ Netanaya, ọmọ Ṣelemaya ọmọ Kuṣi pé kí ó lọ sọ fún Baruku kí ó máa bọ̀ kí ó sì mú ìwé tí ó kà sí etígbọ̀ọ́ gbogbo eniyan lọ́wọ́. Baruku, ọmọ Neraya, sì wá sọ́dọ̀ wọn tòun ti ìwé náà lọ́wọ́ rẹ̀. +Wọ́n ní kí ó jókòó, kí ó kà á fún àwọn, Baruku bá kà á fún wọn. +Nígbà tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú. Wọ́n bá sọ fún Baruku pé, “A gbọdọ̀ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún ọba.” +Wọ́n bi Baruku pé, “Sọ fún wa, báwo ni o ṣe kọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi sílẹ̀? Ṣé Jeremaya ni ó sọ ọ́, tí ìwọ fi ń kọ ọ́ ni, àbí báwo?” +Baruku bá dá wọn lóhùn pé, Jeremaya ni ó sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún òun ni òun fi kọ ọ́ sinu ìwé. +Àwọn ìjòyè bá sọ fún Baruku pé kí òun ati Jeremaya lọ sápamọ́, kí wọn má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ ibi tí wọ́n wà. +“Mú ìwé kíká kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún ọ nípa Israẹli ati Juda ati gbogbo orílẹ̀-èdè sinu rẹ̀. Gbogbo ohun tí mo sọ láti ọjọ́ tí mo ti ń bá ọ sọ̀rọ̀ ní ìgbà ayé Josaya títí di òní, ni kí o kọ. +Àwọn ìjòyè bá fi ìwé náà pamọ́ sinu yàrá Eliṣama akọ̀wé, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní gbọ̀ngàn, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un. +Ọba bá rán Jehudi pé kí ó lọ mú ìwé náà wá, ó sì mú un wá láti inú yàrá Eliṣama, akọ̀wé. Jehudi bá kà á fún ọba ati gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. +Ninu oṣù kẹsan-an ni ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, ọba sì wà ní ilé tíí máa gbé ní àkókò òtútù, iná kan sì wà níwájú rẹ̀ tí ń jó ninu agbada. +Bí Jehudi bá ti ka òpó mẹta tabi mẹrin ninu ìwé náà, ọba yóo fi ọ̀bẹ gé e kúrò, yóo sì jù ú sinu iná tí ń jó níwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe títí ó fi fi ìwé náà jóná tán. +Sibẹ ẹ̀rù kò ba ọba tabi àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò sì fa aṣọ wọn ya. +Elinatani, Dilaaya ati Gemaraya tilẹ̀ bẹ ọba pé kí ó má fi ìwé náà jóná, ṣugbọn kò gbà. +Ọba bá pàṣẹ fún Jerameeli ọmọ rẹ̀, ati Seraaya ọmọ Asirieli, ati Ṣelemaya ọmọ Abideeli, pé kí wọn lọ mú Baruku akọ̀wé, ati Jeremaya wolii wá, ṣugbọn OLUWA fi wọ́n pamọ́. +Lẹ́yìn tí ọba ti fi ìwé náà jóná, ati gbogbo ohun tí Jeremaya ní kí Baruku kọ sinu rẹ̀, OLUWA sọ fún Jeremaya pé, +“Mú ìwé mìíràn kí o tún kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé ti àkọ́kọ́, tí Jehoiakimu, ọba Juda fi jóná sinu rẹ̀. +Ohun tí o óo kọ nípa Jehoiakimu ọba Juda, nìyí: sọ pé èmi OLUWA ní, ṣé ó fi ìwé ti àkọ́kọ́ jóná ni, ó ní, kí ló dé tí a fi kọ sinu rẹ̀ pé dájúdájú, ọba Babiloni ń bọ̀ wá pa ilẹ̀ yìí run ati pé, yóo pa ati eniyan ati ẹranko tí ó wà ninu rẹ̀ run? +Bóyá bí àwọn ará Juda bá gbọ́ nípa ibi tí mò ń gbèrò láti ṣe sí wọn, olukuluku lè yipada kúrò ninu ọ̀nà ibi rẹ̀, kí n lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìdára wọn jì wọ́n.” +Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA níí sọ nípa rẹ̀ ni pé, ẹyọ ọmọ rẹ̀ kan kò ní jọba lórí ìtẹ́ Dafidi. Ìta ni a óo gbé òkú rẹ̀ jù sí, oòrùn yóo máa pa á lọ́sàn-án, ìrì yóo sì máa sẹ̀ sí i lórí lóru. +N óo jẹ òun, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ níyà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo mú kí gbogbo ibi tí mo pinnu lórí wọn ṣẹ sí wọn lára ati sí ara àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn ará Juda, nítorí pé wọn kò gbọ́ràn.” +Jeremaya bá fún Baruku akọ̀wé, ọmọ Neraya, ní ìwé mìíràn, Baruku sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jeremaya sọ fún un sinu rẹ̀. Ó kọ ohun tí ó wà ninu ìwé àkọ́kọ́ tí Jehoiakimu ọba Juda fi jóná, ó sì fi àwọn nǹkan mìíràn kún un pẹlu. +Jeremaya bá pe Baruku ọmọ Neraya, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá a sọ fún un, Baruku bá kọ wọ́n sinu ìwé kíká kan. +Jeremaya pàṣẹ fún Baruku pé, “Wọn kò gbà mí láàyè láti lọ sí inú ilé OLUWA; +nítorí náà, ìwọ ni óo lọ sibẹ ní ọjọ́ ààwẹ̀ láti ka ọ̀rọ̀ tí o gbọ́ ní ẹnu mi; tí o sì kọ sí inú ìwé kíká, sí etí gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wá láti ìlú wọn. +Ó ṣeéṣe kí wọn mú ẹ̀bẹ̀ wọn wá siwaju OLUWA, kí olukuluku sì yipada kúrò lọ́nà ibi rẹ̀ tí ó ń rìn, nítorí pé ibinu OLUWA pọ̀ lórí wọn.” +Baruku bá ṣe gbogbo ohun tí Jeremaya wolii pa láṣẹ fún un lati kà lati inú ìwé ilé Oluwa. +Ní oṣù kẹsan-an, ọdún karun-un tí Jehoiakimu ọmọ Josaya jọba ní Juda, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn eniyan tí wọ́n ti àwọn ìlú Juda wá sí Jerusalẹmu, kéde ọjọ́ ààwẹ̀ níwájú OLUWA. +Ohun Tí Sedekaya Bèèrè lọ́wọ́ Jeremaya. +Nebukadinesari, ọba Babiloni fi Sedekaya, ọmọ Josaya, jọba ní ilẹ̀ Juda dípò Jehoiakini, ọmọ Jehoiakimu. +Bí àwọn ará Juda bá tilẹ̀ ṣẹgun gbogbo ọmọ ogun àwọn ará Kalidea, tí wọ́n gbógun tì wọ́n, títí tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́ nìkan ni wọ́n kù ninu àgọ́ wọn, wọn yóo dìde sí àwọn ará Juda, wọn yóo sì sun ìlú yìí níná. +Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Kalidea ti kúrò ní Jerusalẹmu, nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn ọmọ ogun Farao ń bọ̀, +Jeremaya jáde ní Jerusalẹmu ó fẹ́ lọ sí ilẹ̀ Bẹnjamini kí ó lọ gba ilẹ̀ rẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀. +Bí Jeremaya wolii ti dé bodè Bẹnjamini ọ̀kan ninu àwọn oníbodè tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Irija ọmọ Ṣelemaya ọmọ Hananaya mú un, ó ní, “O fẹ́ sálọ bá àwọn ará Kalidea ni.” +Jeremaya dá a lóhùn, pé, “Rárá o, n kò sálọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kalidea.” Ṣugbọn Irija kọ̀, kò gbọ́, ó sá mú Jeremaya lọ sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè. +Inú bí àwọn ìjòyè sí Jeremaya, wọ́n lù ú, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n ní ilé Jonatani akọ̀wé, nítorí pé wọ́n ti sọ ibẹ̀ di ọgbà ẹ̀wọ̀n. +Lẹ́yìn tí Jeremaya ti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọpọlọpọ ọjọ́, +Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú un wá sí ààfin rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA ranṣẹ kankan?”Jeremaya dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí OLUWA sọ ni pé, a óo fi ọ́ lé ọba Babiloni lọ́wọ́.” +Jeremaya wá bi Sedekaya ọba pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́, tabi àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, tabi àwọn ará ìlú yìí, tí ẹ fi jù mí sẹ́wọ̀n? +Níbo ni àwọn wolii rẹ wà, àwọn tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọ pé, ‘Ọba Babiloni kò ní gbógun ti ìwọ ati ilẹ̀ yìí?’ +Ṣugbọn Sedekaya ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan náà kò pa ọ̀rọ̀ tí OLUWA ní kí Jeremaya wolii sọ fún wọn mọ́. +Nisinsinyii, kabiyesi, oluwa mi, jọ̀wọ́ fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi, má dá mi pada sí ilé Jonatani akọ̀wé, kí n má baà kú sibẹ.” +Sedekaya ọba bá pàṣẹ, wọ́n sì fi Jeremaya sinu gbọ̀ngàn ọgbà àwọn t�� ń ṣọ́ ààfin. Wọ́n sì ń fún un ní burẹdi kan lojumọ láti òpópónà àwọn oníburẹdi títí tí gbogbo burẹdi fi tán ní ìlú. Bẹ́ẹ̀ ni Jeremaya ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé gbọ̀ngàn àwọn tí ń ṣọ́ ààfin. +Ọba Sedekaya rán Jehukali, ọmọ Ṣelemaya, ati Sefanaya, alufaa, ọmọ Maaseaya, sí Jeremaya wolii, pé kí ó jọ̀wọ́ bá àwọn gba adura sí OLUWA Ọlọrun. +Ní àkókò yìí Jeremaya sì ń rìn káàkiri láàrin àwọn eniyan, nítorí wọn kò tíì jù ú sẹ́wọ̀n nígbà náà. +Àwọn ọmọ ogun Farao ti jáde, wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti; nígbà tí àwọn ará Kalidea tí wọn dóti Jerusalẹmu gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀, wọ́n kúrò ní Jerusalẹmu. +OLUWA sọ fún Jeremaya wolii pé kí ó sọ fún àwọn tí ọba Juda rán láti wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ pé, +OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí òun Jeremaya sọ fún ọba pé, àwọn ọmọ ogun Farao tí wọn wá ràn wọ́n lọ́wọ́ ti ń múra láti pada sí Ijipti, ilẹ̀ wọn. +Àwọn ará Kalidea sì ń pada bọ̀ wá gbé ogun ti ìlú yìí; wọn yóo gbà á, wọn yóo sì dáná sun ún. +OLUWA ní kí wọn sọ fún Sedekaya ati àwọn ará Juda kí wọn má tan ara wọn jẹ, kí wọn má sì rò pé àwọn ará Kalidea kò ní pada wá sọ́dọ̀ wọn mọ́, nítorí wọn kò ní lọ. +Wọ́n Ju Jeremaya sinu Kànga Gbígbẹ. +Nígbà tí Ṣefataya, ọmọ Matani, ati Gedalaya, ọmọ Paṣuri, ati Jukali, ọmọ Ṣelemaya, ati Paṣuri ọmọ Malikaya gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremaya ń sọ fún gbogbo àwọn eniyan pé, +Ọba bá pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Etiopia, ó ní, “Mú eniyan mẹta lọ́wọ́, kí ẹ lọ yọ Jeremaya wolii kúrò ninu kànga náà kí ó tó kú.” +Ebedimeleki bá mú àwọn ọkunrin mẹta náà, wọ́n lọ sí yàrá kan ní ilé ìṣúra tí ó wà láàfin ọba. Ó mú àwọn àkísà ati àwọn aṣọ tí wọ́n ti gbó níbẹ̀, ó so okùn mọ́ wọn, ó sì nà án sí Jeremaya ninu kànga. +Ó bá sọ fún Jeremaya pé kí ó fi àwọn àkísà ati àwọn aṣọ tí wọ́n ti gbó náà sí abíyá mejeeji, kí ó fi okùn kọ́ ara rẹ̀ lábíyá. Jeremaya sì ṣe bẹ́ẹ̀. +Wọ́n bá fi okùn fa Jeremaya jáde kúrò ninu kànga. Jeremaya bá ń gbé gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin. +Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú Jeremaya wolii wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà kẹta tí ó wà ní Tẹmpili OLUWA, ó wí fún Jeremaya pé, “Ọ̀rọ̀ kan ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ rẹ, má sì fi ohunkohun pamọ́ fún mi.” +Jeremaya bá wí fún Sedekaya, ó ní, “Bí mo bá sọ fún ọ, o kò ní pa mí dájúdájú? Bí mo bá sì fún ọ ní ìmọ̀ràn, o kò ní gbà.” +Sedekaya ọba bá búra fún Jeremaya ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Mo fi OLUWA alààyè ẹni tí ó dá ẹ̀mí wa búra, pé n kò ní pa ọ́, n kò sì ní fi ọ́ lé àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ lọ́wọ́.” +Jeremaya bá wí fún Sedekaya pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọn ó dá ẹ̀mí rẹ sí, wọn kò sì ní dáná sun ìlú yìí, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ yóo sì yè. +Ṣugbọn bí o kò bá fi ara rẹ le àwọn ìjòyè ọba Babiloni lọ́wọ́, ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Kalidea, wọn yóo sì dáná sun ún, ìwọ pàápàá kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ wọn.” +Sedekaya ọba bá wí fún Jeremaya pé, “Ẹ̀rù àwọn ará Juda tí wọ́n sá lọ bá àwọn ará Kalidea ń bà mí. Wọ́n lè fà mí lé wọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì fi mí ṣẹ̀sín.” +“OLUWA ní, ẹni tí ó bá dúró ní ìlú Jerusalẹmu yóo kú ikú idà, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn; ṣugbọn àwọn tí wọn bá jáde tọ àwọn ará Kalidea lọ yóo yè. Ó ní ọ̀rọ̀ wọn yóo dàbí ẹni tí ó ja àjàbọ́, ṣugbọn yóo wà láàyè. +Jeremaya dáhùn pé, “Wọn kò ní fà ọ́ lé wọn lọ́wọ́. Tẹ̀lé ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń sọ fún ọ; yóo dára fún ọ, a óo sì dá ẹ̀mí rẹ sí. +Ṣugbọn bí o bá kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ ohun tí OLUWA fihàn mí nìyí: +Wò ó, mo rí i tí wọn ń kó àwọn obinrin tí wọ́n wà ní ààfin ọba Juda jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọ́n sì ń wí pé,‘Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí o fọkàn tán tàn ọ́,wọ́n sì ti ṣẹgun rẹ;nisinsinyii tí o rì sinu ẹrẹ̀,wọ́n pada lẹ́yìn rẹ.’ +“Gbogbo àwọn aya rẹ ati àwọn ọmọ rẹ ni wọn yóo kó lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kalidea, ìwọ gan-an kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ọwọ́ ọba Babiloni yóo tẹ̀ ọ́, wọn yóo sì dáná sun ìlú yìí.” +Sedekaya ọba bá kìlọ̀ fún Jeremaya pé, “Má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ gbogbo nǹkan tí a jọ sọ, o kò sì ní kú. +Bí àwọn ìjòyè bá gbọ́ pé a jọ sọ̀rọ̀, bí wọn bá wá só��dọ̀ rẹ tí wọn ní kí o sọ nǹkan tí o bá mi sọ fún àwọn, ati èsì tí mo fún ọ, tí wọn bẹ̀ ọ́ pé kí o má fi ohunkohun pamọ́ fún àwọn, tí wọn sì ṣe ìlérí pé àwọn kò ní pa ọ́, +sọ fún wọn pé ẹ̀bẹ̀ ni ò ń bẹ̀ mí pé kí n má dá ọ pada sí ilé Jonatani; kí o má baà kú sibẹ.” +Gbogbo àwọn ìjòyè tọ Jeremaya lọ, wọ́n bí í, ó sì fún wọn lésì gẹ́gẹ́ bí ọba tí pàṣẹ fún un. Wọ́n bá dákẹ́, nítorí ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n jọ sọ. +Jeremaya bá ń gbé gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin títí di ọjọ́ tí ogun kó Jerusalẹmu. +Ati pé dájúdájú, ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Babiloni, wọn yóo sì gbà á.” +Àwọn ìjòyè náà bá sọ fún ọba pé, “Ẹ jẹ́ kí á pa ọkunrin yìí nítorí pé ó ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ogun tí wọn kù láàrin ìlú, ati gbogbo àwọn eniyan nítorí irú ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún wọn. Ọkunrin yìí kò fẹ́ alaafia àwọn eniyan wọnyi, àfi ìpalára wọn.” +Sedekaya ọba bá dá wọn lóhùn, pé, “Ìkáwọ́ yín ló wà, n kò jẹ́ ṣe ohunkohun tí ó bá lòdì sí ìfẹ́ yín.” +Wọ́n bá mú Jeremaya, wọ́n jù ú sinu kànga Malikaya, ọmọ ọba, tí ó wà ní gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Wọ́n fi okùn sọ Jeremaya kalẹ̀ sinu kànga náà, kò sí omi ninu rẹ̀, àfi ẹrẹ̀ nìkan, Jeremaya sì rì sinu ẹrẹ̀ náà. +Nígbà tí Ebedimeleki ará Etiopia tí ó jẹ́ ìwẹ̀fà ní ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremaya sinu kànga. Ọba wà níbi tí ó jókòó sí ní ibodè Bẹnjamini. +Ebedimeleki jáde ní ààfin, ó lọ bá ọba ó sì wí fún un pé, +“Kabiyesi, oluwa mi, gbogbo nǹkan tí àwọn eniyan wọnyi ṣe sí wolii Jeremaya kò dára. Inú kànga ni wọ́n jù ú sí, ebi ni yóo sì pa á sibẹ nítorí pé kò sí burẹdi ní ìlú mọ́.” +Ìṣubú Jerusalẹmu. +Ní oṣù kẹwaa, ọdún kẹsan-an ìjọba Sedekaya, ọba Juda, Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dótì í. +Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ fi díẹ̀ ninu àwọn talaka sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda, ó sì fún wọn ní ọgbà àjàrà ati oko. +Nebukadinesari ọba Babiloni pàṣẹ fún Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ pé +kí wọn mú Jeremaya, kí wọn tọ́jú rẹ̀ dáradára, kí wọn má pa á lára, ṣugbọn kí wọn ṣe ohunkohun tí ó bá ń fẹ́ fún un. +Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ati Nebuṣasibani, ìjòyè pataki kan, ati Negali Sareseri olóyè pataki mìíràn ati gbogbo àwọn olóyè jàǹkànjàǹkàn ninu àwọn ìjòyè ọba Babiloni, +wọ́n ranṣẹ lọ mú Jeremaya jáde kúrò ní ìgbèkùn. Wọ́n bá fà á lé Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani lọ́wọ́, pé kí ó mú un lọ sí ilé rẹ̀. Ó bá ń gbé ààrin àwọn eniyan náà. +OLUWA sọ fún Jeremaya nígbà tí ó wà ní àtìmọ́lé ní gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba, pé, +kí ó lọ sọ fún Ebedimeleki ará Etiopia pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Wò ó, n óo mú ìpinnu ibi tí mo ṣe lórí ìlú yìí ṣẹ, lójú rẹ ni yóo sì ṣẹ. +N óo gbà ọ́ sílẹ̀ ní ọjọ́ náà, wọn kò ní fà ọ́ lé àwọn tí ò ń bẹ̀rù lọ́wọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Nítorí pé, dájúdájú n óo gbà ọ́ sílẹ̀, o ò ní kú ikú idà, ṣugbọn o óo sá àsálà, nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé mi.” +Ní ọjọ́ kẹsan-an, oṣù kẹrin, ọdún kọkanla ìjọba rẹ̀, wọ́n wọ ìlú náà. +Lẹ́yìn tí ogun ti kó Jerusalẹmu, gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babiloni péjọ, wọ́n sì jókòó ní bodè ààrin: Negali Sareseri, Samgari Nebo, Sarisekimu Rabusarisi, Negali Sareseri, Rabumagi ati àwọn ìjòyè ọba Babiloni yòókù. +Nígbà tí Sedekaya ọba Juda ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ rí wọn, wọ́n sá. Wọ́n fòru bojú, wọ́n bá jáde ní ìlú; wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba, ní ọ̀nà ibodè tí ó wà láàrin odi meji, wọ́n sì dojú kọ ọ̀nà Araba. +Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lé wọn, wọ́n bá Sedekaya ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; wọ́n mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Nebukadinesari ọba Babiloni ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati, ó sì dá Sedekaya lẹ́jọ́. +Ọba Babiloni pa àwọn ọmọ Sedekaya ní Ribila níṣojú rẹ̀, ó sì pa gbogbo àwọn ìjòyè Juda pẹlu. +Ó yọ ojú Sedekaya, ó sì fi ẹ̀wọ̀n bàbà dè é láti mú un lọ sí Babiloni. +Àwọn ará Kalidea jó ààfin ọba ati ilé àwọn ará ìlú, wọ́n sì wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀. +Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ bá kó àwọn eniyan tí wọn ṣẹ́kù ní Jerusalẹmu ní ìgbèkùn, lọ sí Babiloni pẹlu àwọn tí wọn kọ́ sá lọ bá a tẹ́lẹ̀. +Ìpè sí Ìrònúpìwàdà. +OLUWA ní, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, bí ẹ bá fẹ́ yipada, ọ̀dọ̀ mi ni kí ẹ pada sí. Mo kórìíra ìbọ̀rìṣà; nítorí náà bí ẹ bá jáwọ́ ninu rẹ̀, tí ẹ kò bá ṣìnà kiri mọ́, +Mo bá dáhùn pé, “Háà, OLUWA Ọlọrun, àṣé ò ń tan àwọn eniyan wọnyi, ati àwọn ará Jerusalẹmu ni, nígbà tí o sọ fún wọn pé, yóo dára fún wọn; àṣé idà ti dé ọrùn wọn!” +A óo wí fún àwọn eniyan yìí, ati àwọn ará Jerusalẹmu ní ìgbà náà pé afẹ́fẹ́ gbígbóná kan ń fẹ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè, ninu pápá, ó ń fẹ́ bọ̀ sọ́dọ̀ àwọn eniyan mi; kì í ṣe afẹ́fẹ́ lásán tíí fẹ́ pàǹtí ati ìdọ̀tí dànù. +Ìjì tí yóo ti ọ̀dọ̀ mi wá yóo le jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nisinsinyii èmi ni mò ń fi ọ̀rọ̀ mi dá wọn lẹ́jọ́. +Ẹ wò ó! Ó ń bọ̀ bí ìkùukùu,kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ dàbí ìjì.Àwọn ẹṣin rẹ̀ yára ju àṣá lọ.A gbé, nítorí ìparun dé bá wa. +Ìwọ Jerusalẹmu, fọ ibi dànù kúrò lọ́kàn rẹ,kí á lè gbà ọ́ là.Yóo ti pẹ́ tó tí èrò burúkú yóo fi máa wà lọ́kàn rẹ? +Nítorí a gbọ́ ohùn kan láti ilẹ̀ Dani,tí ń kéde ibi láti òkè Efuraimu. +Ẹ kìlọ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè pé ó ń bọ̀,kéde fún Jerusalẹmu pé,àwọn ológun tí ń dó ti ìlú ń bọ̀, láti ilẹ̀ òkèèrè.Wọ́n ń kọ lálá sí àwọn ìlú Juda. +Wọ́n yí i ká bí àwọn tí ó ń ṣọ́ oko,nítorí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA.OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +Ìrìn ẹsẹ̀ rẹ ati ìwà rẹni ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá ọ.Ìjìyà rẹ nìyí, ó sì korò;ó ti dé oókan àyà rẹ. +Oró ò! Oró ò!Mò ń jẹ̀rora!Àyà mi ò!Àyà mi ń lù kìkìkì,n kò sì lè dákẹ́;nítorí mo gbọ́ ìró fèrè ogun, ati ariwo ogun. +tí ẹ bá ń búra pẹlu òtítọ́ pé, ‘Bí OLUWA ti wà láàyè,’ lórí ẹ̀tọ́ ati òdodo, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo máa fi orúkọ mi súre fún ara wọn, wọn yóo sì máa ṣògo ninu mi.” +Àjálù ń ṣubú lu àjálù,gbogbo ilẹ̀ ti parun.Lójijì àgọ́ mi wó lulẹ̀,aṣọ títa mi sì fàya ní ìṣẹ́jú kan. +Yóo ti pẹ́ tó tí n óo máa wo àsíá ogun,tí n óo sì máa gbọ́ fèrè ogun? +OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn eniyan mi gọ̀,wọn kò mọ̀ mí.Òmùgọ̀ ọmọ ni wọ́n;wọn kò ní òye.Ọgbọ́n àtiṣe ibi kún inú wọn:ṣugbọn wọn kò mọ rere ṣe.” +Mo bojú wo ilé ayé, ilé ayé ṣófo,ó rí júujùu;mo ṣíjú wo ojú ọ̀run,kò sí ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀. +Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n ń mì tìtì,gbogbo òkè kéékèèké ń sún lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún. +Mo wò yíká, n kò rí ẹnìkan,gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ti fò sálọ. +Mo wò yíká, mo rí i pé gbogbo ilẹ̀ ọlọ́ràá ti di aṣálẹ̀,gbogbo ìlú sì ti di òkítì àlàpà níwájú OLUWA,nítorí ibinu ńlá rẹ̀. +Nítorí OLUWA ti sọ pé,gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro;sibẹ òpin kò ní tíì dé. +Nítorí èyí, ilẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀,ojú ọ̀run yóo sì ṣókùnkùn.Nítorí pé ó ti sọ bẹ́ẹ̀,ó ti rò ó dáradára, kò tíì jáwọ́ ninu rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní yipada. +Nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin ati ti àwọn tafàtafà,gbogbo ìlú sá jáde fún ààbò.Wọ́n sá wọ inú igbó lọ,wọ́n gun orí òkè lọ sinu pàlàpálá òkúta;gbogbo ìlú sì di ahoro. +Nítorí pé OLUWA sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, “Ẹ tún oko yín tí ẹ ti patì tẹ́lẹ̀ kọ, ẹ má sì gbin èso sáàrin ẹ̀gún. +Ìwọ tí o ti di ahoro,kí ni èrò rẹ tí o fi wọ aṣọ elése àlùkò?Tí o wa nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà sára?Tí o tọ́ ojú?Tí o tọ́ ètè?Asán ni gbogbo ọ̀ṣọ́ tí o ṣe,àwọn olólùfẹ́ rẹ kò kà ọ́ sí,ọ̀nà ati gba ẹ̀mí rẹ ni wọ́n ń wá. +Nítorí mo gbọ́ igbe kan, tí ó dàbí igbe obinrin tí ó ń rọbí,ó ń kérora bí aboyún tí ó ń rọbí alákọ̀ọ́bí.Mo gbọ́ igbe Jerusalẹmu tí ń pọ̀ọ̀kà ikú,tí ó na ọwọ́ rẹ̀ síta, tí ń ké pé,“Mo gbé! Mò ń kú lọ, lọ́wọ́ àwọn apànìyàn!” +Ẹ kọ ara yín ní ilà abẹ́ fún OLUWA, kí ẹ sì kọ ara yín ní ilà ọkàn, ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu; kí ibinu mi má baà dé, bí iná tí ó ń jó tí kò sí ẹni tí ó lè pa á, nítorí iṣẹ́ ibi yín.” +Ẹ sọ ọ́ ní Juda,ẹ sì kéde rẹ̀ láàrin Jerusalẹmu pé,“Ẹ fọn fèrè káàkiri ilẹ̀ náà,kí ẹ sì kígbe sókè pé,‘Ẹ kó ara yín jọ kí á lọ sí àwọn ìlú olódi.’ +Ẹ gbé àsíá sókè sí Sioni,pé kí wọn sá àsálà, kí wọn má ṣe dúró,nítorí mò ń mú ibi ati ìparun ńlá bọ̀ láti ìhà àríwá. +Kinniun kan ti jáde lọ láti inú igbó tí ó wà;ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n máa ń run àwọn orílẹ̀-èdè ti gbéra;ó ti jáde kúrò ní ipò rẹ̀,láti s�� ilẹ̀ yín di ahoro.Yóo pa àwọn ìlú yín run,kò sì ní sí eniyan ninu wọn mọ́. +Nítorí èyí, ẹ fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora,ẹ sọkún kí ẹ máa ké tẹ̀dùntẹ̀dùn,nítorí ìrúnú gbígbóná OLUWAkò tíì yipada kúrò lọ́dọ̀ wa.” +OLUWA ní, “Tó bá di ìgbà náà, ojora yóo mú ọba ati àwọn ìjòyè, àwọn alufaa yóo dààmú, ẹnu yóo ya àwọn wolii.” +Jeremaya Ń Gbé Ọ̀dọ̀ Gedalaya. +OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, tú u sílẹ̀ ní Rama. Nebusaradani rí Jeremaya tí wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, wọ́n sì kó o pọ̀ mọ́ àwọn tí wọn kó kúrò ní ìlú Jerusalẹmu ati ní ilẹ̀ Juda tí wọn ń kó lọ sí Babiloni. +Ní tèmi, Misipa ni n óo máa gbé kí n lè máa rí ààyè bá àwọn ará Kalidea tí wọn wá dótì wá sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin ẹ máa kó ọtí, èso, ati òróró jọ sinu ìkòkò yín, kí ẹ sì máa gbé àwọn ìlú tí ẹ ti gbà.” +Bákan náà, nígbà tí gbogbo àwọn ará Juda tí wọn wà ní ilẹ̀ Moabu, ati àwọn tí wọn wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni ati ti Edomu ati àwọn tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ káàkiri gbọ́ pé ọba Babiloni dá àwọn eniyan díẹ̀ sí ní Juda, àtipé ó fi Gedalaya, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ṣe gomina wọn, +gbogbo àwọn ará Juda pada láti gbogbo ibi tí wọn sá lọ, wọ́n wá sí ilẹ̀ Juda, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa, wọ́n sì kó ọtí ati èso jọ lọpọlọpọ. +Johanani ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko wá sọ́dọ̀ Gedalaya ní Misipa. +Wọ́n sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Baalisi, ọba àwọn ọmọ Amoni ti rán Iṣimaeli, ọmọ Netanaya pé kí ó wá pa ọ́?” Ṣugbọn Gedalaya kò gbà wọ́n gbọ́. +Johanani bá sọ fún Gedalaya ní ìkọ̀kọ̀ ní Misipa pé, “Jẹ́ kí n lọ pa Iṣimaeli ọmọ Netanaya, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀. Kí ló dé tí o óo jẹ́ kí ó pa ọ́, tí gbogbo Juda tí wọn kóra jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ yóo sì túká; tí àwọn tí wọn ṣẹ́kù ninu àwọn eniyan Juda yóo sì ṣègbé?” +Ṣugbọn Gedalaya sọ fún Johanani, ọmọ Karea pé, “Má ṣe bẹ́ẹ̀, irọ́ ni ò ń pamọ́ Iṣimaeli.” +Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Babiloni, sọ fún Jeremaya pé, “OLUWA Ọlọrun rẹ ti pinnu láti ṣe ilẹ̀ yìí ní ibi; +Ó sì ti ṣe bí ó ti pinnu nítorí pé ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí i, ẹ kò sì fetí sí ohùn rẹ̀, nítorí náà ni ibi ṣe dé ba yín. +Nisinsinyii, wò ó, mo tú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ ọwọ́ rẹ sílẹ̀, bí o bá fẹ́ bá mi lọ sí Babiloni, máa bá mi kálọ, n óo tọ́jú rẹ dáradára; bí o kò bá sì fẹ́ lọ, dúró. Wò ó, gbogbo ilẹ̀ nìyí níwájú rẹ yìí, ibi tí o bá fẹ́ tí ó dára lójú rẹ ni kí o lọ. +Bí o bá fẹ́ pada, pada lọ bá Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ẹni tí ọba Babiloni fi ṣe gomina àwọn ìlú Juda, kí o máa bá a gbé láàrin àwọn eniyan náà. Bí o kò bá sì fẹ́ bẹ́ẹ̀, ibi tí ó bá wù ọ́ láti lọ ni kí o lọ.” Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba bá fún un ní owó, oúnjẹ, ati ẹ̀bùn, ó ní kí ó máa lọ. +Jeremaya bá pada sọ́dọ̀ Gedalaya, ọmọ Ahikamu ní Misipa, ó sì ń gbé pẹlu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan tí wọn kù ní ilẹ̀ náà. +Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu jẹ gomina ní ilẹ̀ Juda, ati pé ó ti fi ṣe olùtọ́jú àwọn ọkunrin, ati àwọn obinrin, ati àwọn ọmọde ati díẹ̀ ninu àwọn talaka ilẹ̀ Juda, tí wọn kò kó lọ sí Babiloni, +wọ́n lọ bá Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n lọ nìwọ̀nyí: Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraaya, ọmọ Tanhumeti, àwọn ọmọ Efai, ará Netofa, Jesanaya, ọmọ ará Maakati, àwọn àtàwọn eniyan wọn. +Gedalaya bá búra fún àwọn ati àwọn eniyan wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù ati sin àwọn ará Kalidea. Ẹ máa gbé ilẹ̀ yìí, kí ẹ máa sin ọba Babiloni, yóo sì dára fun yín. +Ní oṣù keje ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ọmọ Eliṣama dé, ìdílé ọba ni ó ti wá, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba. Òun pẹlu àwọn ọkunrin mẹ́wàá bá lọ sọ́dọ̀ Gedalaya ọmọ Ahikamu ní Misipa. Bí wọ́n ṣe ń jẹun lọ́wọ́ ní Misipa, +Iṣimaeli bá kó gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Misipa lẹ́rú, àwọn ọmọ ọba lobinrin ati gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Misipa, àwọn tí Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba fi sí abẹ́ ìṣọ́ Gedalaya. Iṣimaeli kó wọn lẹ́rú ó sì fẹ́ kó wọn kọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Amoni. +Nígbà tí Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ gbọ́ gbogbo iṣẹ́ ibi tí Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ṣe, +wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn lọ gbógun ti Iṣimaeli, wọ́n bá a létí odò ńlá tí ó wà ní Gibeoni. +Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Iṣimaeli rí Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, inú wọn dùn. +Ni gbogbo àwọn tí Iṣimaeli kó lẹ́rú ní Misipa bá yipada kúrò lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n lọ bá Johanani ọmọ Karea. +Ṣugbọn Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, pẹlu àwọn mẹjọ sá àsálà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Amoni. +Lẹ́yìn náà Johanani ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, kó gbogbo àwọn tí Iṣimaeli ọmọ Netanaya kó lẹ́rú ní Misipa, lẹ́yìn tí ó pa Gedalaya ọmọ Ahikamu tán, ó bá kó ati àwọn ọmọ ogun, ati àwọn obinrin, ati àwọn ọmọde, ati àwọn ìwẹ̀fà, pada wá láti Gibeoni. +Wọ́n lọ ń gbé Geruti Kimhamu, tí ó wà lẹ́bàá Bẹtilẹhẹmu. Wọ́n pinnu láti kó lọ sí ilẹ̀ Ijipti nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kalidea ń bà wọ́n; +nítorí pé Iṣimaeli ọmọ Netanaya ti pa Gedalaya, ọmọ Ahikamu, tí ọba Babiloni fi ṣe gomina ilẹ̀ náà. +Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ati àwọn mẹ́wàá tí wọ́n bá a wá dìde, wọ́n bá fi idà pa Gedalaya tí ọba Babiloni fi ṣe gomina ilẹ̀ náà. +Iṣimaeli pa gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà pẹlu Gedalaya ní Misipa, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà níbẹ̀. +Ọjọ́ keji tí wọ́n pa Gedalaya tán, kí ẹnikẹ́ni tó gbọ́ nípa rẹ̀, +àwọn ọgọrin eniyan kan wá láti Ṣekemu, Ṣilo ati láti Samaria pẹlu irùngbọ̀n wọn ní fífá, wọ́n fa agbádá wọn ya, wọ́n sì ṣá ara wọn lọ́gbẹ́. Wọ́n mú ọrẹ ẹbọ ati turari lọ́wọ́ wá sí Tẹmpili OLUWA. +Iṣimaeli, ọmọ Netanaya sọkún pàdé wọn láti Misipa. Bí ó ti pàdé wọn ó wí pé, “Ẹ máa kálọ sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ọmọ Ahikamu.” +Nígbà tí wọ́n wọ ààrin ìlú, Iṣimaeli ọmọ Netanaya ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì kó òkú wọn dà sí inú kòtò. +Ṣugbọn àwọn mẹ́wàá kan ninu wọn sọ fún Iṣimaeli pé, “Má pa wá, nítorí a ní ọkà wíítì, ọkà baali, ati òróró ati oyin ní ìpamọ́ ninu oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀ kò sì pa wọ́n bí ó ti pa àwọn yòókù wọn. +Kòtò tí Iṣimaeli ju òkú àwọn eniyan tí ó pa sí ni kòtò tí ọba Asa gbẹ́ tí ó fi dí ọ̀nà mọ́ Baaṣa ọba Israẹli; ṣugbọn Iṣimaeli, ọmọ Netanaya fi òkú eniyan tí ó pa kún kòtò náà. +Àwọn Eniyan náà Ní kí Jeremaya Gbadura fún Àwọn. +Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn olórí ogun ati Johanani, ọmọ Karea ati Asaraya, ọmọ Hoṣaaya, ati gbogbo àwọn ará Juda, lọ́mọdé ati lágbà, tọ wolii Jeremaya lọ. +‘Bí ẹ bá dúró ní ilẹ̀ yìí, n óo kọ yín bí ilé, n kò sì ní wo yín lulẹ̀. N óo gbìn yín bí igi, n kò sì ní fà yín tu, nítorí mo ti yí ọkàn mi pada nípa ibi tí mo ṣe sí yín. +Ẹ má bẹ̀rù ọba Babiloni tí ẹrù rẹ̀ ń bà yín, ẹ má bẹ̀rù rẹ̀; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, nítorí pé mo wà pẹlu yín. N óo gbà yín là n óo sì yọ yín lọ́wọ́ rẹ̀. +N óo ṣàánú yín, n óo jẹ́ kí ó ṣàánú yín, kí ó sì jẹ́ kí ẹ máa gbé orí ilẹ̀ yín.’ +“Bí ẹ bá wí pé ẹ kò ní dúró ní ilẹ̀ yìí, tí ẹ kò sì gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu; +bí ẹ bá ń wí pé, ‘Rárá o, a óo sá lọ sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí a kò ti ní gbúròó ogun tabi fèrè ogun, níbi tí ebi kò ti ní pa wá, a óo sì máa gbé ibẹ̀,’ +ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin tí ẹ ṣẹ́kù ní Juda. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Bí ẹ bá gbójú lé àtilọ sí Ijipti, pé ẹ óo lọ máa gbé ibẹ̀, ogun tí ẹ̀ ń sá fún yóo bá yín níbẹ̀; +ìyàn tí ẹ̀ ń bẹ̀rù yóo tẹ̀lé yín lọ sí Ijipti; ebi tí ẹ páyà rẹ̀ yóo gbá tẹ̀lé yín, ibẹ̀ ni ẹ óo sì kú sí. +Gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbójú lé àtilọ sí Ijipti láti máa gbé ibẹ̀ yóo kú ikú ogun, ati ti ìyàn pẹlu àjàkálẹ̀ àrùn, wọn kò ní ṣẹ́kù, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni wọn kò ní bọ́ ninu ibi tí n óo mú wá sórí wọn.’ +“Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Bí mo ti bínú sí àwọn ará Jerusalẹmu, tí inú mi sì ń ru sí wọn, bẹ́ẹ̀ ni n óo bínú si yín nígbà tí ẹ bá dé Ijipti. Ẹ óo di ẹni ègún, ẹni àríbẹ̀rù, ẹni ẹ̀gàn ati ẹni ẹ̀sín. Ẹ kò sì ní fojú kan ilẹ̀ yìí mọ́.’ +“OLUWA ti sọ fún ẹ̀yin tí ẹ ṣẹ́kù ní Juda pé kí ẹ má lọ sí Ijipti. Ẹ mọ̀ dájúdájú pé mo kìlọ̀ fun yín lónìí +Wọ́n wí fún un pé, “Nǹkan kan ni a fẹ́ bẹ̀ ọ́ fún, a sì f��̣ kí o ṣe é fún wa: jọ̀wọ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ fún àwa ati gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, nítorí pé a ti pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn díẹ̀ ninu wa ni ó kù, bí ìwọ náà ti fi ojú ara rẹ rí i. +pé ẹ ti fi ẹ̀mí ara yín wéwu nítorí ìṣìnà yín. Nítorí pé nígbà tí ẹ rán mi sí OLUWA Ọlọrun yín pé kí n gbadura fun yín, gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yín bá wí ni kí n sọ fun yín, ẹ ní ẹ óo sì ṣe é. +Mo ti sọ ohun tí Ọlọrun wí fun yín lónìí, ṣugbọn ẹ kò tẹ̀lé ọ̀kan kan ninu ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ní kí n sọ fun yín. +Nítorí náà ẹ mọ̀ dájú pé ẹ óo kú ikú ogun, ati ti ìyàn pẹlu àjàkálẹ̀ àrùn, ní ibi tí ẹ fẹ́ lọ máa gbé.” +A fẹ́ kí OLUWA Ọlọrun rẹ lè fi ọ̀nà tí a óo gbà hàn wá, kí ó sọ ohun tí a óo ṣe fún wa.” +Wolii Jeremaya bá dá wọn lóhùn pé, “Mo gbọ́, n óo gbadura sí OLUWA Ọlọrun yín bí ẹ ti wí; gbogbo ìdáhùn tí OLUWA bá fún mi ni n óo sọ fun yín, n kò ní fi nǹkankan pamọ́.” +Wọ́n wí fún Jeremaya pé, “Kí OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ ati òdodo bí a kò bá ṣe gbogbo nǹkan tí OLUWA Ọlọrun bá ní kí o sọ fún wa. +Ìbáà jẹ́ rere ni OLUWA Ọlọrun wa tí a rán ọ sí sọ, kì báà jẹ́ burúkú, a óo gbọ́ràn sí i lẹ́nu; kí ó lè dára fún wa; nítorí pé ti OLUWA Ọlọrun wa ni a óo gbọ́.” +Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwaa, OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀. +Jeremaya bá pe Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan, ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki. +Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ẹ ní kí n gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ siwaju rẹ̀ ní, +Wọ́n Mú Jeremaya Lọ sí Ijipti. +Nígbà tí Jeremaya parí gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn rán an sí gbogbo àwọn ará ìlú, +kí o sì wí fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun óo lọ mú Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ òun wá, yóo sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ka orí àwọn òkúta tí òun rì mọ́lẹ̀ yìí, Nebukadinesari yóo sì tẹ́ ìtẹ́ ọlá rẹ̀ sórí wọn. +Yóo wá kọlu ilẹ̀ Ijipti, yóo jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn tí yóo kú ikú àjàkálẹ̀ àrùn, yóo kó àwọn tí yóo lọ sí ìgbèkùn lọ sí ìgbèkùn, yóo sì fi idà pa àwọn tí yóo kú ikú idà. +Yóo dáná sun àwọn ilé àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti; yóo jó wọn níná; yóo sì kó àwọn ará ìlú lọ sí ìgbèkùn; yóo fọ ilẹ̀ Ijipti mọ́ bí darandaran tíí ṣa eégbọn kúrò lára aṣọ rẹ̀, yóo sì jáde kúrò níbẹ̀ ní alaafia. +Yóo fọ́ àwọn òpó ilé oriṣa Heliopolisi tí ó wà ní ilẹ̀ Ijipti, yóo sì dáná sun àwọn ilé àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti.” +Asaraya, ọmọ Hoṣaaya, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn ọkunrin aláfojúdi kan wí fún Jeremaya pé, “Irọ́ ni ò ń pa. OLUWA Ọlọrun wa kò rán ọ láti sọ fún wa pé kí á má lọ ṣe àtìpó ní Ijipti. +Baruku, ọmọ Neraya, ni ó fẹ́ mú wa kọlù ọ́, kí o lè fà wá lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, kí wọ́n lè pa wá; tabi kí wọ́n kó wa lọ sí ìgbèkùn ní Babiloni.” +Nítorí náà Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun ati gbogbo àwọn ará ìlú kò gba ohun tí OLUWA sọ, pé kí wọ́n dúró ní ilẹ̀ Juda. +Kàkà bẹ́ẹ̀, Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun kó gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọ́n pada wá sí ilẹ̀ Juda láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti sálọ: +àwọn ọkunrin ati àwọn obinrin, àwọn ọmọde, àwọn ìjòyè, ati gbogbo àwọn tí Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Babiloni, fi sábẹ́ àkóso Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Jeremaya wolii ati Baruku ọmọ Neraya. +Wọ́n kó wọn lọ sí ilẹ̀ Ijipti, nítorí wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ OLUWA Ọlọrun wọn. Wọ́n lọ títí tí wọ́n fi dé Tapanhesi. +OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní Tapanhesi: +Ó ní, “Gbé òkúta ńláńlá lọ́wọ́, kí o bò wọ́n mọ́lẹ̀, níbi pèpéle tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà ààfin Farao ní Tapanhesi, lójú àwọn ará Juda, +Iṣẹ́ Tí OLUWA Rán sí Àwọn Ọmọ Israẹli ní Ijipti. +Nǹkan tí Jeremaya gbọ́ nípa gbogbo àwọn Juu tí wọn ń gbé Migidoli ati Tapanhesi, ati Memfisi ati ilẹ̀ Patirosi ní ilẹ̀ Ijipti nìyí. +Wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ títí di òní, tabi kí wọn bẹ̀rù, tabi kí wọ́n pa òfin ati ìlànà tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba yín mọ́.’ +“Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹ wò ó, n óo dójúlé yín, n óo sì pa gbogbo ọmọ Juda run. +N óo run gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní ilẹ̀ Juda tí wọ́n gbójú lé àtilọ máa gbé ilẹ̀ Ijipti, wọn kò ní ku ẹyọ kan ní ilẹ̀ Ijipti. Gbogbo wọn ni wọn óo parun láti orí àwọn mẹ̀kúnnù dé orí àwọn eniyan pataki pataki; ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n. Wọn yóo di ẹni ìfibú, ẹni àríbẹ̀rù, ẹni ègún ati ẹni ẹ̀sín. +N óo fìyà jẹ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti, n óo fi ogun, ìyàn, ati àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n run bí mo ṣe fi pa Jerusalẹmu run. +Ẹnikẹ́ni kò ní yè ninu àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Juda, tí wọ́n lọ fi ilẹ̀ Ijipti ṣe ilé; wọn kò ní sá àsálà, wọn kò sì ní yè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní pada sí ilẹ̀ Juda tí ọkàn wọn fẹ́ pada sí. Wọn kò ní pada, àfi àwọn bíi mélòó kan ni wọ́n óo sá àsálà.’ ” +Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n mọ̀ pé àwọn iyawo wọn ń sun turari sí àwọn oriṣa ati àwọn obinrin tí wọ́n pọ̀ gbáà tí wọn wà nítòsí ibẹ̀, ati àwọn tí wọn ń gbé Patirosi ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n bá dá Jeremaya lóhùn, +wọ́n ní, “A kò ní fetí sì ọ̀rọ̀ tí ò ń bá wa sọ lórúkọ OLUWA. +Ṣugbọn a óo máa san gbogbo ẹ̀jẹ́ wa, a óo máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, oriṣa wa, a óo sì máa ta ohun mímu sílẹ̀, bí àwa ati àwọn baba ńlá wa, ati àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa ti ṣe ní gbogbo ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu; nítorí pé nígbà náà à ń jẹ oúnjẹ ní àjẹyó, ó dára fún wa, ojú wa kò sì rí ibi. +Ṣugbọn láti ìgbà tí a ti dáwọ́ ati máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run dúró, tí a kò sì máa ta ohun mímu sílẹ̀ mọ́, ni a kò ti ní nǹkankan mọ́, tí ogun ati ìyàn sì fẹ́ẹ̀ pa wá tán.” +Àwọn obinrin bá tún dáhùn pé, “Nígbà tí à ń sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ ohun mímu sí i, ṣé àwọn ọkọ wa ni kò mọ̀ pé à ń ṣe àkàrà dídùn, tí à ń ṣe bí ère rẹ̀ fún un ni, ati pé à ń ta ohun mímu sílẹ̀ fún un?” +OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Ẹ rí gbogbo ibi tí mo jẹ́ kí ó bá Jerusalẹmu ati gbogbo ìlú Juda. Ẹ wò wọ́n lónìí bí wọ́n ti di ahoro, tí kò sì sí eniyan ninu wọn, +Jeremaya sọ fún gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n dá a lóhùn, lọkunrin ati lobinrin pé: +“Ṣebí OLUWA ranti turari tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín, ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín, ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà sun ninu àwọn ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu, ṣebí OLUWA ranti. +OLUWA kò lè farada ìwà burúkú tí ẹ̀ ń hù, ati àwọn nǹkan ìríra tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí náà, ni ilẹ̀ yín ṣe di ahoro ati aṣálẹ̀, ati ilẹ̀ tí a fi ń gégùn-ún, tí kò ní olùgbé, títí di òní. +Ìdí tí èyí fi ṣẹlẹ̀ si yín ni pé ẹ sun turari, ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ kò fetí sí ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ kò pa òfin, ati ìlànà rẹ̀ mọ́.” +Jeremaya dá gbogbo àwọn eniyan náà lóhùn, pataki jùlọ àwọn obinrin, ó ní, “Ẹ gbọ́ nǹkan tí OLUWA sọ, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ Ijipti, +OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹ̀yin ati àwọn iyawo yín ti fi ẹnu ara yín sọ, ẹ sì ti fi ọwọ́ ara yín mú ohun tí ẹ wí ṣẹ pé, “Dájúdájú a ti jẹ́jẹ̀ẹ́ sí oriṣa ọbabinrin ojú ọ̀run láti sun turari sí i, ati láti rú ẹbọ ohun mímu sí i.” ’ Kò burú, ẹ mú ẹ̀jẹ́ yín ṣẹ! +Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ Ijipti: Ó ní, ‘Ẹ wò ó, mo ti fi orúkọ ńlá mi búra pé àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Ijipti kò ní fi orúkọ mi búra mọ́ pé “Bí OLUWA ti wà láàyè.” +Mo dójúlé yín láti ṣe yín ní ibi. Ibi ni n óo ṣe yín, n kò ní ṣe yín ní oore. Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Ijipti ni ogun ati ìyàn yóo pa láìku ẹnìkan. +Àwọn eniyan díẹ̀ ni wọn yóo sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Ijipti lọ sí ilẹ̀ Juda. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda, tí wọ́n lọ sí Ijipti yóo wá mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóo ṣẹ, bóyá tèmi ni, tabi tiwọn. +Èyí ni yóo jẹ́ àmì fun yín pé n óo jẹ yín níyà ní ilẹ̀ yìí, kí ẹ lè mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ibi tí mo sọ si yín yóo ṣẹ mọ yín lára, +nítorí ibi tí wọ́n ṣe, wọ́n mú mi bínú nítorí pé wọ́n sun turari sí àwọn oriṣa tí àwọn tabi àwọn baba wọn kò mọ̀ rí, wọ́n sì ń sìn wọ́n. +Èmi OLUWA ni mo sọ ọ́ pé n óo fi Farao Hofira ọba Ijipti lé ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekaya, ọba Juda lé ọwọ́ ọ̀tá rẹ̀, Nebukadinesari, ọba Babiloni, ẹni tí ó ń wá ọ̀nà láti pa á.’ ” +Sibẹsibẹ mo rán gbogbo àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, sí wọn, kí wọ́n sọ fún wọn pé kí wọn má ṣe ohun ìríra tí n kò fẹ́. +Ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọn kò fetí sílẹ̀, wọn kò dáwọ́ ibi ṣíṣe dúró, wọn kò sì yé sun turari sí oriṣa mọ́. +Mo bá bínú gan-an sí àwọn ìlú Juda ati ìgboro Jerusalẹmu; mo sì sọ wọ́n di aṣálẹ̀ ati ahoro bí wọ́n ti wà lónìí. +“Èmi, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli wá ń bi yín léèrè pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe ara yín ní ibi tó báyìí? Ṣé ẹ fẹ́ kó gbogbo àwọn eniyan wọnyi kúrò ní ilẹ̀ Juda, ati àwọn ọkunrin ati àwọn obinrin, àtọmọ ọmú, àtọmọ ọwọ́, títí tí kò fi ní ku ẹnikẹ́ni ninu yín lẹ́yìn ni? +Kí ló dé tí ẹ fi ń fi iṣẹ́ ọwọ́ yín bí mi ninu, tí ẹ̀ ń sun turari sí àwọn oriṣa ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ̀ ń gbé? Ṣé ẹ fẹ́ kí n pa yín run, kí ẹ di ẹni ẹ̀sín láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni ẹ ṣe ń ṣe báyìí? +Ṣé ẹ ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín ṣe ní ilẹ̀ Juda ati ìgboro Jerusalẹmu, tí àwọn ọba Juda ati àwọn ayaba ṣe ati ẹ̀yin pẹlu àwọn iyawo yín? +Ìlérí Ọlọrun fún Baruku. +Ọ̀rọ̀ tí Jeremaya wolii sọ fún Baruku ọmọ Neraya nìyí, ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya, jọba ní Juda. Baruku ń kọ ohun tí Jeremaya ń sọ sílẹ̀ bí Jeremaya tí ń sọ̀rọ̀. +Ó ní: “OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún ìwọ Baruku pé, +ò ń sọ pé, o gbé, nítorí pé OLUWA ti fi ìbànújẹ́ kún ìrora rẹ; àárẹ̀ mú ọ nítorí ìkérora rẹ, o kò sì ní ìsinmi. +“Èmi ń wó ohun tí mo kọ́ lulẹ̀, mo sì ń tu ohun tí mo gbìn, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ gbogbo ilẹ̀ náà rí. +Ìwọ ń wá nǹkan ńlá fún ara tìrẹ? Má wá nǹkan ńlá fún ara rẹ. Wò ó, n óo mú kí ibi bá gbogbo eniyan, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀; ṣugbọn n óo jẹ́ kí o máa sá àsálà ní gbogbo ibi tí o bá ń lọ.” +Nebukadinesari ṣẹgun Ijipti ní Kakemiṣi. +Ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá Jeremaya wolii sọ nípa àwọn orílẹ̀-èdè nìyí. +Ọjọ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ọjọ́ náà,ọjọ́ ẹ̀san, tí yóo gbẹ̀san ara rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.Idà rẹ̀ yóo pa àpatẹ́rùn, yóo sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn ní àmuyó.Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní ń rúbọ,ní ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate. +Gòkè lọ sí Gileadi, kí o lọ wá ìwọ̀ra, ẹ̀yin ará Ijipti,asán ni gbogbo òògùn tí ẹ lò,ẹ kò ní rí ìwòsàn. +Àwọn orílẹ̀ èdè ti gbọ́ nípa ìtìjú yín,igbe yín ti gba ayé kan;nítorí àwọn ọmọ ogun ń rọ́ lu ara wọn;gbogbo wọn sì ṣubú papọ̀. +Ohun tí OLUWA sọ fún wolii Jeremaya nípa Nebukadinesari, ọba Babiloni nígbà tí ó ń bọ̀ wá ṣẹgun ilẹ̀ Ijipti nìyí: +Ó ní, “Ẹ kéde ní Ijipti,ẹ polongo ní Migidoli, ní Memfisi ati ní Tapanhesi.Ẹ wí pé, ‘Ẹ gbáradì kí ẹ sì múra sílẹ̀,nítorí ogun yóo run yín yíká. +Kí ló dé tí àwọn akọni yín kò lè dúró?Wọn kò lè dúró nítorí péOLUWA ni ó bì wọ́n ṣubú.’ +Ogunlọ́gọ̀ yín ti fẹsẹ̀ kọ, wọ́n sì ṣubú,wọ́n wá ń wí fún ara wọn pé,‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wa,ati sí ilẹ̀ tí wọn gbé bí wa,nítorí ogun àwọn aninilára.’ +“Ẹ pa orúkọ Farao, ọba Ijipti dà,ẹ pè é ní, ‘Aláriwo tí máa ń fi anfaani rẹ̀ ṣòfò.’ +Ọba, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun,fi ara rẹ̀ búra pé, bí òkè Tabori ti rí láàrin àwọn òkè,ati bí òkè Kamẹli létí òkun,bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan tí yóo yọ si yín yóo rí. +Ẹ di ẹrù yín láti lọ sí ìgbèkùn, ẹ̀yin ará Ijipti!Nítorí pé Memfisi yóo di òkítì àlàpà,yóo di ahoro, kò sì ní sí ẹni tí yóo máa gbé ibẹ̀. +Ọ̀rọ̀ lórí Ijipti: Nípa àwọn ọmọ ogun Farao Neko, ọba Ijipti, tí wọ́n wà létí odò Yufurate ní Kakemiṣi, àwọn tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, ṣẹgun ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu ọmọ Josaya jọba Juda. +Ijipti dàbí ọmọ mààlúù tí ó lẹ́wà,ṣugbọn irù kan, tí ó ti ìhà àríwá fò wá, ti bà lé e. +Àwọn ọmọ ogun tí ó fi owó bẹ̀ lọ́wẹ̀,dàbí akọ mààlúù àbọ́pa láàrin rẹ̀;àwọn náà pẹ̀yìndà, wọ́n ti jọ sálọ,wọn kò lè dúró;nítorí ọjọ́ ìdààmú wọn ti dé bá wọn,ọjọ́ ìjìyà wọn ti pé. +Ó ń dún bí ejò tí ó ń sálọ;nítorí pé àwọn ọ̀tá rẹ̀ ń bọ̀ tagbára tagbára,wọ́n ń kó àáké bọ̀ wá bá a,bí àwọn tí wọn ń gé igi. +Wọn yóo gé igi inú igbó rẹ̀ lulẹ̀.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó náà dí,nítorí pé igi ibẹ̀ pọ̀ bí eṣú, tí wọn kò sì lóǹkà. +A óo dójú ti àwọn ará Ijipti,a óo fà wọ́n lé àwọn ará ìhà àríwá lọ́wọ́.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: “N óo fi ìyà jẹ Amoni, oriṣa Tebesi, ati Farao, ati Ijipti pẹlu àwọn oriṣa rẹ̀, ati àwọn ọba rẹ̀. N óo fìyà jẹ Farao ati àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e. +N óo fà wọ́n lé àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́; n óo fà wọ́n fún Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn eniyan yóo máa gbé Ijipti bíi ti àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +“Ṣugbọn ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,ọmọ Israẹli, ẹ má fòyà;n óo gbà yín là láti ọ̀nà jíjìn,n óo kó arọmọdọmọ yín yọ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ óo pada máa gbé ní ìrọ̀rùn.Kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rù bà yín. +Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi, nítorí pé mo wà pẹlu yín.N óo run gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo le yín lọ,ṣugbọn n kò ní pa yín run.Bí ó bá tọ́ kí n jẹ yín níyà, n óo jẹ yín níyà,kìí ṣe pé n óo fi yín sílẹ̀ láìjẹ yín níyà.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +“Ọ̀gágun Ijipti pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé,‘Ẹ tọ́jú asà ati apata,kí ẹ sì jáde sójú ogun! +Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣin, ẹ di ẹṣin yín ní gàárì, kí ẹ sì gùn wọ́n.Ẹ dúró ní ipò yín, pẹlu àṣíborí lórí yín.Ẹ pọ́n àwọn ọ̀kọ̀ yín,kí ẹ gbé ihamọra irin yín wọ̀!’ ” +Oluwa ní, “Kí ni mo rí yìí?Ẹ̀rù ń bà wọ́n, wọ́n sì ń pada sẹ́yìn.A ti lu àwọn ọmọ ogun wọn bolẹ̀,wọ́n sì ń sálọ pẹlu ìkánjú;wọn kò bojú wẹ̀yìn, ìpayà yí wọn ká! +Àwọn tí ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ kò lè sálọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun kò lè sá àsálà.Ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate, ni wọ́n tí fẹsẹ̀ kọ, tí wọ́n sì ṣubú. +Ta ló ń ru bí odò Naili yìí,bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀? +Ijipti ń ru bí odò Naili,bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀.Ijipti wí pé, ‘N óo kún, n óo sì bo ayé mọ́lẹ̀,n óo pa àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn run. +Ó yá, ẹṣin, ẹ gbéra,kí kẹ̀kẹ́ ogun máa sáré kíkankíkan!Kí àwọn ọmọ ogun máa nìṣó,àwọn ọmọ ogun Etiopia ati Puti, tí wọ́n mọ asà á lò,àwọn ọmọ ogun Ludi, tí wọ́n mọ ọfà á ta dáradára.’ ” +Iṣẹ́ tí OLUWA Rán sí Àwọn Ará Filistia. +OLUWA bá Jeremaya wolii sọ̀rọ̀ nípa Filistini kí Farao tó ṣẹgun Gasa, +Ó ní,“Wò ó, omi kan ń ru bọ̀ láti ìhà àríwá,yóo di àgbàrá tí ó lágbára;yóo ya bo ilẹ̀ yìí ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,yóo ya bo ìlú yìí pẹlu, ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.Àwọn eniyan yóo kígbe: gbogbo àwọn ará ìlú yóo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. +Nígbà tí pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin bá ń dún,tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ bá ń sáré,tí ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sì ń pariwo,Àwọn baba kò ní lè wo àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn pé kí àwọn fà wọ́n,nítorí pé ọwọ́ wọn yóo rọ; +nítorí ọjọ́ tí ń bọ̀, tí yóo jẹ́ ọjọ́ ìparun gbogbo àwọn ará Filistia,ọjọ́ tí a óo run gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ tí ó kù fún Tire ati Sidoni.Nítorí pé OLUWA yóo pa àwọn ará Filistia run,àwọn tí wọ́n kù ní etí òkun ní Kafitori. +Ìbànújẹ́ ti dé bá Gasa, Aṣikeloni ti parun.Ẹ̀yin tí ẹ kù lára àwọn ọmọ Anakimu, ẹ óo ti fi ìbànújẹ́ ṣá ara yín lọ́gbẹ́ pẹ́ tó? +Ẹ̀yin ń bèèrè pé, ‘Ìwọ idà OLUWA,yóo ti pẹ́ tó kí o tó sinmi?Pada sinu àkọ̀ rẹ, máa sinmi kí o sì dúró jẹ́ẹ́.’ +Ṣugbọn idà OLUWA ṣe lè dákẹ́ jẹ́ẹ́, nígbà tí Oluwa fún un ní iṣẹ́ láti ṣe? OLUWA ti pàṣẹ fún un láti kọlu Aṣikeloni, ati àwọn ìlú etí òkun.” +Ìparun Moabu. +OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Moabu pé,“Nebo gbé nítorí yóo di ahoro!Ojú yóo ti Kiriataimu nítorí ogun óo kó o;ìtìjú yóo bá ibi ààbò rẹ̀, wọn óo wó o lulẹ̀; +(Ègún ń bẹ lórí ẹni tí ó bá ń fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ OLUWA;ègún sì ń bẹ lórí ẹni tí ó bá sì kọ̀, tí kò máa fi idà rẹ̀ pa eniyan.) +OLUWA ní,“Láti ìgbà èwe Moabu ni ó ti ń gbé pẹlu ìrọ̀rùn,kò tíì lọ sí ìgbèkùn rí.Nítorí náà ó silẹ̀ bí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ọtí.A kò máa dà á kiri láti inú ìgò kan sí òmíràn.Adùn rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀, òórùn rẹ̀ kò sì tíì yipada. +“Nítorí náà, àkókò ń bọ̀,tí n óo jẹ́ kí wọn da Moabu nù, bí ẹni da ọtí nù.Àwọn tí wọn ń da ọtí nù ni n óo rán, tí wọn óo wá tẹ̀ ẹ́ bí ìgò ọtíwọn óo dà á nù patapata, wọn óo sì fọ́ ìgò rẹ̀. +Kemoṣi yóo di ohun ìtìjú fún Moabu,gẹ́gẹ́ bí Bẹtẹli, tí Israẹli gbójú lé, ṣe di ohun ìtìjú fún Israẹli. +Ẹ ṣe lè wí pé alágbára ni yín, ati pé ẹ jẹ́ akikanju lójú ogun? +Ẹni tí yóo pa ilẹ̀ Moabu ati àwọn ìlú rẹ̀ run ti dé,àwọn àṣàyàn ọmọkunrin rẹ̀ sì ti lọ sí ibi tí wọn ó ti pa wọ́n.Èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni ó sọ bẹ́ẹ̀. +Ọjọ́ ìdààmú Moabu fẹ́rẹ̀ dé, ìpọ́njú rẹ̀ sì ń bọ̀ kánkán. +“Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ yí i ká, ẹ dárò rẹ̀,kí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ orúkọ rẹ̀ sì wí pé,‘Ọ̀pá àṣẹ tí ó lágbára ti kán,ọ̀pá àṣẹ tí ó lógo ti ṣẹ́.’ +Sọ̀kalẹ̀ kúrò ninu ògo rẹ, kí o jókòó lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, ìwọ tí ò ń gbé Diboni!Nítorí pé ẹni tí óo pa Moabu run ti dojú kọ ọ́,ó sì ti wó àwọn ibi ààbò rẹ̀. +Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o máa ṣọ́nà, ìwọ tí ò ń gbé Aroeri!Bèèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n sálọ; bi àwọn tí ń sá àsálà pé, ‘Kí ló ṣẹlẹ̀?’ +ògo Moabu ti dópin!Wọ́n ń pète ibi sí i ní Heṣiboni,wọ́n ní, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ pa á run, kí ó má jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́!’Ẹ̀yin ará Madimeni pàápàá, kẹ́kẹ́ yóo pa mọ yín lẹ́nu;ogun yóo máa le yín kiri. +Ìtìjú ti bá Moabu, nítorí pé ó ti wó lulẹ̀; ẹ kígbe, ẹ máa sọkún.Ẹ kéde rẹ̀ ní ipadò Anoni, pé,‘Moabu ti parẹ́, ó ti di òkítì àlàpà.’ +“Ìdájọ́ ti dé sórí àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú: Holoni, Jahisai, ati Mefaati; +Diboni, Nebo, ati Beti Dibilataimu, +Kiriataimu, Betigamuli, ati Betimeoni, +Kerioti, Bosira, ati gbogbo àwọn ìlú ilẹ̀ Moabu, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ati àwọn tí wọ́n wà lókèèrè. +Ipá Moabu ti pin, a sì ti ṣẹ́ ẹ lápá. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA ní,“Ẹ rọ Moabu lọ́tí yó,nítorí pé ó gbéraga sí OLUWA;kí ó lè máa yíràá ninu èébì rẹ̀,a óo sì fi òun náà ṣẹ̀sín. +Moabu, ṣebí ò ń fi Israẹli ṣe yẹ̀yẹ́?Ṣé o bá a láàrin àwọn ọlọ́ṣà ni,tí ó fi jẹ́ pé nígbàkúùgbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ń ṣe ni o máa ń mi orí rẹ? +“Ẹ fi ààrin ìlú sílẹ̀, kí ẹ lọ máa gbé inú àpáta, ẹ̀yin ará Moabu!Ẹ ṣe bí àdàbà, tí ó kọ́lé rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ẹnu ihò àpáta. +A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu,ó ní ìgbéraga lọpọlọpọ,a ti gbọ́ nípa èrò gíga rẹ̀, ati ìgbéraga rẹ̀,nípa àfojúdi rẹ̀, ati nípa ìwà ìjọra-ẹni-lójú rẹ̀. +Gbọ́ igbe kan ní Horonaimu,igbe ìsọdahoro ati ìparun ńlá! +Mo mọ̀ pé aláfojúdi ni.Ó ń fọ́nnu lásán ni, kò lè ṣe nǹkankan tó yanjú. +Nítorí náà, ni mo ṣe ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, tí mò ń kígbe sókè nítorí Moabutí mo sì ń ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn ará Kiri Heresi. +Ìwọ ọgbà àjàrà Sibima,ọ̀rọ̀ rẹ pa mí lẹ́kún, ju ti Jaseri lọ!Àwọn ẹ̀ka rẹ tàn dé òkun, wọ́n tàn títí dé Jaseri,apanirun sì ti kọlu àwọn èso ẹ̀ẹ̀rùn rẹ, ati èso àjàrà rẹ. +Wọ́n ti mú ayọ̀ ati ìdùnnú kúrò ní ilẹ̀ ọlọ́ràá Moabu;mo ti mú kí ọtí waini tán níbi tí wọ́n ti ń ṣe é,kò sí ẹni tí ó ń ṣe ọtí waini pẹlu ariwo ayọ̀ mọ́, ariwo tí wọn ń pa kì í ṣe ti ayọ̀. +“Heṣiboni ati Eleale kígbe sókè, igbe wọn sì dé Jahasi láti Soari, ó dé Horonaimu ati Egilati Ṣeliṣiya. Àwọn odò Nimrimu pàápàá ti gbẹ. +N óo pa àwọn tí ń rú ẹbọ níbi pẹpẹ ìrúbọ run, ati àwọn tí ń sun turari sí oriṣa ní ilẹ̀ Moabu. +“Nítorí náà ni mo ṣe ń dárò Moabu ati àwọn ará Kiri Heresi bí ẹni fi fèrè kọ orin arò nítorí pé gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n kó jọ ti ṣègbé. +Gbogbo wọn ti fá irun orí ati irùngbọ̀n wọn; wọ́n ti fi abẹ ya gbogbo ọwọ́ wọn, wọ́n sì lọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìbàdí. +Gbogbo eniyan ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ní gbogbo orí ilé Moabu, ati àwọn ìta gbangba rẹ̀. Nítorí pé mo ti fọ́ Moabu, bíi ohun èlò tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +A ti fọ́ Moabu túútúú! Ẹ̀ ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn! Moabu pẹ̀yìndà pẹlu ìtìjú! Moabu wá di ẹni yẹ̀yẹ́ ati ẹni àríbẹ̀rù fún gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká.” +“Moabu ti parun; a gbọ́ igbe àwọn ọmọ rẹ̀. +OLUWA ní,“Wò ó, ẹnìkan yóo fò wá bí ẹyẹ idì,yóo sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ lé Moabu lórí. +Ogun yóo kó àwọn ìlú Moabu,wọn óo sì gba àwọn ibi ààbò rẹ̀.Ní ọjọ́ náà, ọkàn àwọn ọmọ ogun Moabu yóo dàbí ọkàn obinrin tí ó ń rọbí, +Moabu yóo parun, kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́,nítorí pé ó ṣe ìgbéraga sí OLÚWA. +Ẹ̀yin ará Moabu,ìpayà, ọ̀gbun ati tàkúté ń bẹ níwájú yín! +Ẹni tí ó ń sálọ nítorí ìpayà,yóo jìn sinu ọ̀gbun,ẹni tí ó bá sì jáde ninu ọ̀gbunyóo kó sinu tàkúté.N óo mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá Moabunígbà tí àkókò ìjìyà rẹ̀ bá tó.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Àwọn tí wọn ń sá fún ogun dúró ní ibi ààbò Heṣiboni,wọn kò lágbára mọ́,nítorí iná ṣẹ́ jáde láti Heṣiboniahọ́n iná sì yọ láàrin ilé Sihoni ọba;iná ti jó Moabu tíí ṣe adé àwọn ọmọ onídàrúdàpọ̀ ní àjórun, +Ẹ̀yin ará Moabu, ẹ gbé!Ó ti parí fun yín, ẹ̀yin ọmọ Kemoṣi,nítorí a ti kó àwọn ọmọkunrin yín lẹ́rú,a ti kó àwọn ọmọbinrin yín lọ sí ìgbèkùn. +“Sibẹsibẹ n óo dá ire Moabu pada lẹ́yìn ọ̀la, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún Moabu.” +Bí wọn tí ń gun òkè Luhiti, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọkún,nítorí pé nígbà tí wọn tí ń lọ níbi ẹsẹ̀ òkè Horonaimu,ni wọ́n tí ń gbọ́ igbe ìparun; pé, +‘Ẹ sá! Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín!Ẹ sáré bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aṣálẹ̀!’ +“Ọwọ́ yóo tẹ ìwọ náà, Moabu, nítorí pé o gbójú lé ibi ààbò ati ọrọ̀ rẹ.Oriṣa Kemoṣi yóo lọ sí ìgbèkùn, pẹlu àwọn babalóòṣà ati àwọn ìjòyè rẹ̀. +Apanirun yóo wọ gbogbo ìlú,ìlú kankan kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀;àwọn àfonífojì yóo pòórá, a óo sì pa àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Ẹ bá Moabu wá ìyẹ́, nítorí yóo fò bí ẹyẹ;àwọn ìlú rẹ̀ yóo di ahoro, kò ní ku ẹnikẹ́ni ninu wọn.” +Ìdájọ́ OLUWA Lórí Amoni. +Ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn ará Amoni nìyí: Ó ní,“Ṣé Israẹli kò lọ́mọ ni?Tabi kò ní àrólé?Kí ló dé tí àwọn tí ń bọ Milikomu ṣe gba ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi,tí wọ́n sì fi àwọn ìlú Gadi ṣe ibùjókòó? +Ṣugbọn mo ti tú àwọn ọmọ Esau sí ìhòòhò,Mo ti sọ ibi tí wọn ń sápamọ́ sí di gbangba,wọn kò sì rí ibi sápamọ́ sí mọ́.Àwọn ọmọ wọn ti parun,pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn aládùúgbò wọn;àwọn pàápàá sì ti di àwátì. +Fi àwọn ọmọ rẹ, aláìníbaba sílẹ̀,n óo pa wọ́n mọ́ láàyè,sì jẹ́ kí àwọn opó rẹ gbẹ́kẹ̀lé mi. +“Bí àwọn tí kò yẹ kí wọ́n jìyà bá jìyà, ṣé ìwọ wá lè lọ láìjìyà? O kò ní lọ láìjìyà, dájúdájú ìyà óo jẹ ọ́. +Nítorí pé mo ti fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, pé Bosira yóo di àríbẹ̀rù ati ohun ẹ̀gàn, ahoro ati ohun àmúgégùn-ún; àwọn ìlú rẹ̀ yóo sì di ahoro títí lae.” +Mo ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA,wọ́n ti rán ikọ̀ kan sí àwọn orílẹ̀-èdè,wọ́n ní kí wọn kéde pé,“OLUWA ní, ‘Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ kọlu Edomu,ẹ dìde, kí ẹ gbógun tì í! +Nítorí pé n óo sọ ọ́ di kékeréláàrin àwọn orílẹ̀-èdè,o óo sì di yẹpẹrẹ,láàrin àwọn ọmọ eniyan. +Ẹ̀rù tí ó wà lára rẹ, ati ìgbéraga ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ,ìwọ tí ò ń gbé pàlàpálá àpáta,tí o fi góńgó orí òkè ṣe ibùgbé.Bí o tilẹ̀ kọ́ ìtẹ́ rẹ sí ibi gíga, bíi ti ẹyẹ idì,n óo fà ọ́ lulẹ̀ láti ibẹ̀.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” +OLUWA ní, “Edomu yóo sì di ibi àríbẹ̀rù, ẹ̀rù yóo máa ba gbogbo àwọn tí wọ́n bá gba ibẹ̀ kọjá, wọn yóo máa pòṣé nítorí ibi tí ó dé bá a. +Yóo rí fún un bí ó ti rí fún Sodomu ati Gomora ati àwọn ìlú agbègbè wọn tí ó parun. Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Wò ó, bí kinniun tií yọ ní aginjù odò Jọdani láti kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí Edomu n óo sì mú kí ó sá kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ lójijì. N óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀; nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí? +Nítorí náà, wò ó, àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ kí ariwo ogun sọ, ní Raba ìlú àwọn ọmọ Amoni;Raba yóo di òkítì àlàpà,a óo sì dáná sun àwọn ìgbèríko rẹ̀;Israẹli yóo wá pada fi ogun kó àwọn tí wọ́n kó o lẹ́rú. +Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí OLUWA pa lórí Edomu, ati èrò rẹ̀ lórí àwọn tí wọn ń gbé Temani. A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ, ibùjẹ àwọn ẹran wọn yóo parun nítorí tiwọn. +Ariwo wíwó odi Edomu wọn yóo mi ilẹ̀ tìtì, a óo sì gbọ́ ìró rẹ̀ títí dé etí òkun pupa. +Wò ó! Ẹnìkan yóo fò bí ẹyẹ idì, yóo na ìyẹ́ rẹ̀ sórí Bosira, ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ọmọ ogun Edomu yóo dàbí ọkàn obinrin tí ń rọbí.” +Ohun tí OLUWA sọ nípa Damasku nìyí, Ó ní,“Ìdààmú dé bá Hamati ati Aripadi,nítorí pé wọ́n gbọ́ ìròyìn burúkú:Jìnnìjìnnì dà bò wọ́n, ọkàn wọn sì dàrú,bí omi òkun tí kò lè dákẹ́ jẹ́ẹ́. +Àárẹ̀ mú Damasku,ó pẹ̀yìndà pé kí ó máa sálọ,ṣugbọn ìpayà mú un,ìrora ati ìbànújẹ́ sì dé bá a, bí obinrin tí ń rọbí. +Ẹ wò ó bí ìlú olókìkí tí ó kún fún ayọ̀, ṣe di ibi ìkọ̀sílẹ̀! +Àwọn ọdọmọkunrin Damasku yóo ṣubú ní gbàgede rẹ̀ ní ọjọ́ náà,gbogbo àwọn ọmọ ogun ibẹ̀ yóo sì parun ni;Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +N óo dáná sun odi Damasku, yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi.” +OLUWA sọ nípa Kedari ati àwọn ìjọba Hasori tí Nebukadinesari ọba Babiloni ṣẹgun pé,“Ẹ dìde kí ẹ gbógun ti Kedari!Ẹ pa àwọn ará ìlà oòrùn run! +Ogun yóo kó àgọ́ wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ,ati àwọn aṣọ àgọ́, ati ohun ìní wọn;Ọ̀tá yóo kó ràkúnmí wọn lọ,àwọn eniyan yóo máa kígbe sí wọn pé,‘Ìpayà wà ní gbogbo àyíká.’ +Sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ìwọ Heṣiboni,nítorí pé ìlú Ai ti parun!Ẹ sọkún, ẹ̀yin ọmọbinrin Raba!Ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀,ẹ máa sọkún, kí ẹ sì máa sá sókè sódò láàrin ọgbà!Nítorí pé oriṣa Moleki yóo lọ sí ìgbèkùn,pẹlu àwọn babalóòṣà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ní ibi ìsìn rẹ̀. +“Ẹ̀yin ará Hasori, ẹ sá,ẹ lọ jìnnà réré, kí ẹ sì máa gbé inú ọ̀gbun.Nítorí pé Nebukadinesari, ọba Babiloni ń pète ibi si yín,ó ti pinnu ibi si yín. +Ó ní, ‘Ẹ dìde kí ẹ gbógun ti orílẹ̀-èdè tí ó wà ní alaafia, ati láìléwu,ìlú tí ó dá dúró tí kò sì ní ìlẹ̀kùn tabi ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn fún ààbò.’ +“Àwọn ràkúnmí ati agbo ẹran wọn yóo di ìkógun.N óo fọ́n àwọn tí wọn ń gé ẹsẹ̀ irun wọn ká sí igun mẹrẹẹrin ayé,n óo sì mú kí ibi bá wọn láti gbogbo àyíká wọn. +Hasori yóo di ibùgbé ajáko,yóo di ahoro títí laelae.Ẹnìkan kò ní gbé ibẹ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ mọ́.” +OLUWA àwọn ọmọ ogun bá Jeremaya wolii sọ nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda. +Ó ní, “Wò ó! N óo pa àwọn tafàtafà Elamu, tí wọn jẹ́ orísun agbára wọn, +n óo mú kí ẹ̀fúùfù mẹrin láti igun mẹrẹẹrin ojú ọ̀run kọlu Elamu; n óo sì fọ́n wọn ká sinu ẹ̀fúùfù náà, kò sì ní sí orílẹ̀-èdè kan tí àwọn ará Elamu kò ní fọ́n ká dé. +N óo dẹ́rùbà wọ́n; níwájú àwọn ọ̀tá wọn, ati níwájú àwọn tí ń wá ọ̀nà ati pa wọ́n. N óo bínú sí wọn gan-an, n óo sì mú kí ibi dé bá wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo rán ogun tẹ̀lé wọn, títí n óo fi pa wọ́n tán. +N óo tẹ́ ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu, n óo sì pa ọba ati àwọn ìjòyè wọn. +Ṣugbọn nígbẹ̀yìn, n óo dá ire Elamu pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Kí ló dé tí ò ń fọ́nnu nípa agbára rẹ,ipá rẹ ti pin, ìwọ olóríkunkun ọmọbinrinìwọ tí o gbójú lé ọrọ̀ rẹ,tí ò ń wí pé, ‘Ta ló lè dojú kọ mí?’ +Wò ó! N óo kó ìpayà bá ọ,láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n yí ọ ká;èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Gbogbo yín ni yóo fọ́nká,tí olukuluku yóo sì yà sí ọ̀nà tirẹ̀,kò sì ní sí ẹni tí yóo kó àwọn tí ń sá fún ogun jọ. +“Ṣugbọn lẹ́yìn náà, n óo dá ire àwọn ará Amoni pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa Edomu nìyí: Ó ní,“Ṣé kò sí ọgbọ́n ní Temani mọ́ ni?Àbí àwọn amòye kò ní ìmọ̀ràn lẹ́nu mọ́?Ṣé ọgbọ́n ti rá mọ́ wọn ninu ni? +Ẹ̀yin ará Dedani, ẹ pada kíá, ẹ máa sálọ.Ẹ wọ inú ihò lọ, kí ẹ lọ máa gbébẹ̀!Nítorí pé ní ìgbà tí mo bá jẹ ìran Esau níyà, n óo mú kí ibi dé bá wọn. +Bí àwọn tí ń kórè èso àjàrà bá bẹ̀rẹ̀ sí kórè,ṣebí wọn a máa fi èso díẹ̀ díẹ̀ sílẹ̀?Bí àwọn olè bá wọlé lóru,ṣebí ìba ohun tí ó bá wù wọ́n ni wọn yóo kó? +Ọlọrun kọ Israẹli sílẹ̀. +Máa sáré lọ, sáré bọ̀ ní àwọn òpópónà Jerusalẹmu,wò yíká, kí o sì ṣàkíyèsí rẹ̀!Wo àwọn gbàgede rẹ̀, bóyá o óo rí ẹnìkan,tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo,tí ó sì ń fẹ́ òtítọ́,tí mo fi lè torí rẹ̀ dáríjì Jerusalẹmu. +Kọjá lọ láàrin ọgbà àjàrà rẹ̀ ní poro ní poro, kí o sì pa á run,ṣugbọn má ṣe pa gbogbo rẹ̀ run tán.Gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,nítorí pé wọn kì í ṣe ti OLUWA. +Nítorí pé ilé Israẹli ati ilé Juda ti ṣe alaiṣootọ sí mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Àwọn eniyan yìí ti sọ ọ̀rọ̀ èké nípa OLUWA,wọ́n ní, “OLUWA kọ́! Kò ní ṣe nǹkankan;ibi kankan kò ní dé bá wa,bẹ́ẹ̀ ni a kò ní rí ogun tabi ìyàn.” +Àwọn wolii yóo di àgbá òfo;nítorí kò sí ọ̀rọ̀ OLUWA ninu wọn.Bí wọ́n ti wí ni ọ̀rọ̀ yóo rí fún wọn. +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní,“Nítorí ohun tí wọ́n sọ yìí,wò ó, n óo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi di iná lẹ́nu rẹ.N óo sì jé�� kí àwọn eniyan wọnyi dàbí igi,iná yóo sì jó wọn run. +Ẹ wò ó, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli,mò ń mú orílẹ̀-èdè kan bọ̀ wá ba yín, láti ilẹ̀ òkèèrè,tí yóo ba yín jà.Láti ayé àtijọ́ ni orílẹ̀-èdè ọ̀hún ti wà,orílẹ̀-èdè alágbára ni.Ẹ kò gbọ́ èdè wọn,ẹ kò sì ní mọ ohun tí wọ́n ń sọ. +Apó ọfà wọn dàbí isà òkú tó yanu sílẹ̀,alágbára jagunjagun ni gbogbo wọn. +Wọn yóo jẹ yín ní oúnjẹ,wọn yóo sì kó gbogbo ìkórè oko yín lọ,wọn yóo run àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin.Wọn yóo run ẹran ọ̀sìn yín,ati àwọn mààlúù yín.Wọn yóo run èso ọgbà àjàrà yín, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ yín.Idà ni wọn yóo fi pa àwọn ìlú olódi yín tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé run.” +OLUWA ní, “Ṣugbọn sibẹ, ní gbogbo àkókò yìí, n kò ní pa yín run patapata, +nígbà tí àwọn eniyan bá bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí wa?’ Ẹ óo le dá wọn lóhùn pé bí ẹ ṣe kọ èmi OLUWA sílẹ̀, tí ẹ sì ń bọ oriṣa àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.” +Lóòótọ́ ni wọ́n ń fi orúkọ mi búra pé, “Bí OLUWA tí ń bẹ,”sibẹ èké ni ìbúra wọn. +OLUWA ní, “Kéde rẹ̀ ní ilẹ̀ Jakọbu,sì ṣe ìfilọ̀ rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda: +Ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin òmùgọ̀, aláìlọ́gbọ́n, ẹ̀yin tí ẹ lójú, ṣugbọn tí ẹ kò ríran;ẹ létí, ṣugbọn tí ẹ kò gbọ́ràn. +Ẹ̀rù mi kò tilẹ̀ bà yín? Èmi OLUWA ni mò ń bi yín léèrè.Ẹ wà níwájú mi ẹ kò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.Èmi tí mo fi iyanrìn pààlà fún omi òkun,tí òkun kò sì gbọdọ̀ rékọjá rẹ̀ títí ayé!Bí ó tilẹ̀ ń ru sókè, kò lágbára kan,kí ìgbì rẹ̀ máa hó yaya, kò lè kọjá ààlà náà. +Ṣugbọn ọkàn ẹ̀yin eniyan wọnyi le, ọlọ̀tẹ̀ sì ni yín.Ẹ ti yapa, ẹ sì ti ṣáko lọ. +Ẹ kò sì rò ó lọ́kàn yín, kí ẹ wí pé:‘Ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun wa,tí ó ń fún wa ní òjò lákòókò rẹ̀,ati òjò àkọ́rọ̀ ati àrọ̀kẹ́yìn;OLUWA tí ó ń bá wa mú ọjọ́ ìkórè lọ́wọ́,tí kì í jẹ́ kí àsìkò ìkórè ó yẹ̀.’ +Àìdára yín ti yí ìgbà wọnyi pada,ẹ̀ṣẹ̀ yín ti dínà ohun rere fun yín. +“Àwọn eniyan burúkú wà láàrin àwọn eniyan mi,wọ́n ń dọdẹ eniyan bí ẹni dọdẹ ẹyẹ,wọ́n dẹ tàkúté, wọ́n fi ń mú eniyan. +Ilé wọn kún fún ìwà ọ̀dàlẹ̀,bíi kùùkú tí ó kún fún ẹyẹ.Nítorí èyí, wọ́n di eniyan ńlá,wọ́n di olówó, +wọ́n sanra, ara wọn sì ń dán.Ṣugbọn iṣẹ́ ibi wọn kò ní ààlà.Wọn kìí dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún aláìníbaba,kí ó lè rí ẹ̀tọ́ rẹ̀ gbà;wọn kò sì jẹ́ gbèjà aláìní,kí wọ́n bá a dáàbò bo ẹ̀tọ́ rẹ̀ nílé ẹjọ́. +Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?Kí n má gbẹ̀san ara mi, lára irú orílẹ̀-èdè yìí? +OLUWA, ṣebí òtítọ́ ni ò ń fẹ́?Ò ń nà wọ́n ní pàṣán, ṣugbọn kò dùn wọ́n,o tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́,ṣugbọn wọn kò gbọ́ ìbáwí.Ojú wọn ti dá, ó le koko,wọ́n kọ̀, wọn kò ronupiwada. +Nǹkan burúkú tó yani lẹ́nu,ní ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà: +Àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké,àwọn alufaa ń sọ ọ̀rọ̀ èké àwọn wolii di òfin,àwọn eniyan mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.Ṣugbọn kí ni wọ́n óo ṣe nígbà tí òpin bá dé?” +Nígbà náà ní mo wí lọ́kàn ara mi pé,“Àwọn aláìní nìkan nìwọ̀nyí,wọn kò gbọ́n;nítorí wọn kò mọ ọ̀nà OLUWA,ati òfin Ọlọrun wọn. +N óo lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan pataki pataki,n óo sì bá wọn sọ̀rọ̀;nítorí àwọn mọ ọ̀nà OLUWA,ati òfin Ọlọrun wọn.”Ṣugbọn gbogbo wọn náà ni wọ́n ti fa àjàgà wọn dá,tí wọ́n sì ti kọ àṣẹ ati àkóso OLUWA. +Nítorí náà, kinniun inú igbó ni yóo wá kì wọ́n mọ́lẹ̀.Ìkookò inú aṣálẹ̀ ni yóo wá jẹ wọ́n run.Àmọ̀tẹ́kùn yóo ba dè wọ́n ní àwọn ìlú wọn,tí ẹnikẹ́ni bá jáde ní ìlú,yóo fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀,nígbà pupọ ni wọ́n sì ti yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun. +OLUWA bi Israẹli pé,“Báwo ni mo ṣe lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn ọ́?Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀,wọ́n sì ti ń fi àwọn ohun tí kì í ṣe ọlọrun búra.Nígbà tí mo bọ́ wọn ní àbọ́yó tán,wọ́n ṣe àgbèrè,wọ́n dà lọ sí ilé àwọn alágbèrè. +Wọ́n dàbí akọ ẹṣin tí a kò tẹ̀ lọ́dàá, tí ó yó,olukuluku wọn ń lé aya aládùúgbò rẹ̀ kiri. +Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí? +Ogun kó Babiloni. +OLUWA bá wolii Jeremaya sọ̀rọ̀ nípa Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea pé: +Ohun ìní àwọn ará Kalidea yóo di ìkógun; gbogbo àwọn tí wọn yóo kó wọn lẹ́rù ni yóo kó ẹrù ní àkótẹ́rùn, Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA ní, “Ẹ̀yin ará Babiloni, tí ẹ kó àwọn eniyan mi,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú yín dùn ẹ sì ń yọ̀,tí ẹ sì ń ṣe ojúkòkòrò, bí akọ mààlúù tí ń jẹko ninu pápá,tí ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin: +Ojú yóo ti olú-ìlú yín lọpọlọpọ,a óo dójú ti ilẹ̀ ìbí yín.Wò ó! Yóo di èrò ẹ̀yìn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,yóo di aṣálẹ̀ tí ó gbẹ. +Nítorí ibinu gbígbóná OLUWA,ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́;yóo di ahoro patapata;ẹnu yóo ya gbogbo ẹni tí ó bá gba Babiloni kọjá,wọn yóo sì máa pòṣé nítorí ìyà tí a fi jẹ ẹ́. +“Ẹ gbógun ti Babiloni yíká, gbogbo ẹ̀yin tafàtafà. Ẹ máa ta á lọ́fà, ẹ má ṣẹ́ ọfà kankan kù, nítorí pé ó ti ṣẹ OLUWA. +Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ yí i ká, ẹ hó bò ó, ó ti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn ibi ààbò rẹ̀ ti wó, àwọn odi rẹ̀ sì ti wó lulẹ̀. Nítorí ẹ̀san OLUWA ni, ẹ gbẹ̀san lára rẹ̀; ẹ ṣe sí i bí òun náà ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn. +Ẹ pa àwọn afunrugbin run ní Babiloni, ati àwọn tí ń lo dòjé ní ìgbà ìkórè. Olukuluku yóo pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, yóo sì sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀, nítorí idà àwọn aninilára.” +OLUWA ní, “Israẹli dàbí aguntan tí àwọn kinniun ń lé kiri. Ọba Asiria ni ó kọ́kọ́ fi ṣe ẹran ìjẹ, ọba Babiloni sì ń wó àwọn egungun rẹ̀ tí ó kù. +Nítorí náà èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ ọba Babiloni ati ilẹ̀ rẹ̀ níyà, bí mo ṣe jẹ ọba Asiria níyà. +N óo mú Israẹli pada sí ibùjẹ rẹ̀, yóo máa jẹ oúnjẹ tí ó bá hù lórí òkè Kamẹli ati ní agbègbè Baṣani, yóo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn lórí òkè Efuraimu ati òkè Gileadi. +“Kéde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,ta àsíá, kí o sì kéde.Má fi ohunkohun pamọ́; sọ pé,‘Ogun tí kó Babiloni,ojú ti oriṣa Bẹli,oriṣa Merodaki wà ninu ìdààmú.Ojú ti àwọn ère rẹ̀, ìdààmú sì bá wọn.’ +OLUWA ní, Nígbà tí ó bá yá, tí àkókò bá tó, a óo wá ẹ̀ṣẹ̀ tì ní Israẹli ati Juda; nítorí pé n óo dáríjì àwọn tí mo bá ṣẹ́kù.” +OLUWA ní,“Ẹ gbógun ti ilẹ̀ Merataimu, ati àwọn ará Pekodi.Ẹ pa wọ́n, kí ẹ sì run wọ́n patapata.Gbogbo nǹkan tí mo pàṣẹ fun yín ni kí ẹ ṣe.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +A gbọ́ ariwo ogun ati ìparun ńlá, ní ilẹ̀ náà. +Ẹ wo bí a ti gé òòlù tó ti ń lu gbogbo ayé lulẹ̀,tí a sì fọ́ ọ!Ẹ wo bí Babiloni ti di ohun àríbẹ̀rù, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. +Mo dẹ tàkúté sílẹ̀ fun yín, ẹ̀yin ará Babiloni:Tàkúté náà mu yín, ẹ kò sì mọ̀.Wọ́n ri yín, ọwọ́ sì tẹ̀ yín,nítorí pé ẹ yájú sí èmi OLUWA. +Mo ti ṣí ìlẹ̀kùn ilé ìṣúra àwọn nǹkan ìjà yín,mo sì kó àwọn ohun ìjà ibinu yín jáde,nítorí èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní iṣẹ́ kan láti ṣe ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea. +Ẹ gbógun tì í ní gbogbo ọ̀nà,ẹ ṣí àká rẹ̀ sílẹ̀,ẹ kó o jọ bí òkítì ọkà,kí ẹ sì pa á run patapata,ẹ má dá ohunkohun sí ninu rẹ̀. +Ẹ pa gbogbo akọ mààlúù rẹ̀,ẹ fà wọ́n lọ sí ibi tí wọ́n ti ń pa ẹran.Àwọn ará Babiloni gbé, nítorí ọjọ́ wọn ti pé,àní ọjọ́ ìjìyà wọn.” +(Ẹ gbọ́ ariwo bí àwọn eniyan tí ń sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Babiloni, wá sí Sioni, láti wá ròyìn ìgbẹ̀san Ọlọrun wa, ẹ̀san tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.) +“Ẹ pe àwọn tafàtafà jọ, kí wọn dojú kọ Babiloni; kí gbogbo àwọn tí wọn ń tafà pàgọ́ yí i ká, kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá àsálà. Ẹ san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ ṣe sí i bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn; nítorí pé ó ṣe àfojúdi sí OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli. +“Nítorí pé orílẹ̀-èdè kan láti ìhà àríwá ti gbógun tì í,yóo sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro,kò sì ní sí ẹni tí yóo gbé inú rẹ̀ mọ́,ati eniyan ati ẹranko, wọn óo sá kúrò níbẹ̀. +Nítorí náà àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀, yóo kú ní gbàgede rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní a óo parun ní ọjọ́ náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Wò ó! Mo dojú kọ ọ́,ìwọ onigbeeraga yìí,nítorí pé ọjọ́ ti pé tí n óo jẹ ọ́ níyà.Èmi OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Agbéraga, o óo fẹsẹ̀ kọ, o óo sì ṣubú,kò ní sí ẹni tí yóo gbé ọ dìde.N óo dá iná kan ninu àwọn ìlú rẹ,iná náà yóo sì jó gbogbo àyíká rẹ.” +OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “À ń ni àwọn ọmọ Israẹli lára, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ Juda; gbogbo àwọn tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn ni wọ́n wo ọwọ́ mọ́ wọn, wọn kò jẹ́ kí wọn lọ. +Ṣugbọn alágbára ni Olùràpadà wọn, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Dájúdájú, yóo jà fún wọn, kí ó lè fún ayé ní ìsinmi, ṣugbọn kí ìdààmú lè bá àwọn ará Babiloni.” +OLUWA ní,“Idà ni yóo pa àwọn ará Kalidea,idà ni yóo pa àwọn ará Babiloni,ati àwọn ìjòyè wọn,ati àwọn amòye wọn! +Idà ni yóo pa àwọn awoṣẹ́ wọn,kí wọ́n lè di òpè!Idà ni yóo pa àwọn ọmọ ogun wọn,kí wọ́n lè parẹ́! +Idà ni yóo pa àwọn ẹṣin wọn,ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn,idà ni yóo pa gbogbo àwọn àjèjì ọmọ ogun tí wọ́n wà láàrin wọn,Kí wọ́n lè di obinrin!Idà ni yóo fọ́ àwọn ilé ìṣúra wọn,kí wọ́n lè di ìkógun! +Ọ̀dá yóo dá ní ilẹ̀ wọn,kí àwọn odò wọn lè gbẹ!Nítorí pé ilẹ̀ tí ó kún fún ère ni,wọ́n sì kúndùn ìbọ̀rìṣà. +“Nítorí náà àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati ìkookò ni yóo máa gbé inú Babiloni, ẹyẹ ògòǹgò yóo máa gbé inú rẹ̀. Kò ní sí eniyan níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò ní gbé inú rẹ̀ mọ́ títí lae. +“Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Juda, yóo jọ wá pẹlu ẹkún, wọn yóo máa wá OLUWA Ọlọrun wọn. +Yóo dàbí ìgbà tí Ọlọrun pa Sodomu ati Gomora run, pẹlu àwọn ìlú tí ó yí wọn ká; nítorí náà ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò ní máa dé sibẹ. +“Wò ó! Àwọn kan ń bọ̀ láti ìhà àríwá, orílẹ̀-èdè ńlá, ati ọpọlọpọ ọba,wọ́n ń gbára wọn jọ láti máa bọ̀ láti òkèèrè. +Wọ́n kó ọrun ati ọ̀kọ̀ lọ́wọ́,ìkà ni wọ́n, wọn kò ní ojú àánú.Ìró wọn dàbí ìró rírú omi òkun;wọ́n gun ẹṣin,wọ́n tò bí àwọn ọmọ ogun.Wọ́n ń bọ̀ wá dojú kọ ọ́, ìwọ Babiloni! +Nígbà tí ọba Babiloni gbọ́ ìró wọn,ọwọ́ rẹ̀ rọ,ìrora sì mú un bíi ti obinrin tí ń rọbí. +“Wò ó! Bí kinniun tíí yọ ní aginjù odò Jọdani tíí kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí àwọn ará Babiloni, n óo mú kí wọn sá kúrò lórí ilẹ̀ wọn lójijì; n óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀. Nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí? +Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí èmi OLUWA pa lórí Babiloni, ati èrò mi lórí àwọn ará Kalidea: A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ; ibùjẹ ẹran wọn yóo sì parun nítorí tiwọn. +Ariwo wíwó odi Babiloni yóo mi ilẹ̀ tìtì, a óo sì gbọ́ ìró rẹ̀ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.” +Wọn yóo bèèrè ọ̀nà Sioni, wọn yóo kọjú sibẹ, wọn yóo sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á darapọ̀ mọ́ OLUWA, kí á sì bá a dá majẹmu ayérayé, tí a kò ní gbàgbé mọ́ títí ayé.’ +“Àwọn eniyan mi dàbí aguntan tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́ wọn ti ṣì wọ́n lọ́nà. Wọ́n ń lọ síhìn-ín, sọ́hùn-ún lórí òkè, wọ́n ń ti orí òkè kéékèèké bọ́ sí orí òkè ńláńlá; wọ́n ti gbàgbé ọ̀nà agbo wọn. +Gbogbo àwọn tí wọn rí wọn ń pa wọ́n jẹ, àwọn ọ̀tá wọn sì ń wí pé, ‘A kò ní ẹ̀bi kankan, nítorí pé wọ́n ti ṣẹ OLÚWA, tí ó jẹ́ ibùgbé òdodo wọn, ati ìrètí àwọn baba wọn.’ +“Ẹ sá kúrò láàrin Babiloni, ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, bí òbúkọ tí ó ṣáájú agbo ẹran. +Nítorí n óo rú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè sókè, láti ìhà àríwá, n óo sì kó wọn wá, wọn óo wá dóti Babiloni, wọn yóo gbógun tì í. Ibẹ̀ ni ọwọ́ wọn yóo ti tẹ̀ ẹ́, tí wọn óo sì fogun kó o. Ọfà wọn dàbí akọni ọmọ ogun, tí kì í pada sílé lọ́wọ́ òfo. +Ọlọrun Tún Dá Babiloni lẹ́jọ́ sí i. +OLUWA ní,“Wò ó! N óo gbé ẹ̀mí apanirun kan dìde sí Babiloni,ati sí àwọn ará Kalidea; +OLUWA ti dá wa láre;ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ ròyìn iṣẹ́ OLUWA Ọlọrun wa ní Sioni. +Ẹ pọ́n ọfà yín!Ẹ gbé asà yín!Nítorí OLUWA ti ru ẹ̀mí àwọn ọba Media sókè,nítorí pé ó ti pinnu láti pa Babiloni run.Ẹ̀san OLUWA ni, ẹ̀san nítorí tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó. +Ẹ gbé àsíá kan sókè, ẹ gbé e ti odi Babiloni;ẹ ṣe ìsénà tí ó lágbára.Ẹ fi àwọn aṣọ́nà sí ipò wọn;ẹ dira fún àwọn kan, kí wọn sápamọ́,nítorí OLUWA ti pinnu, ó sì ti ṣe ohun tí ó sọ nípa àwọn ará Babiloni. +Ìwọ Babiloni, tí odò yí ká, tí ìṣúra rẹ pọ̀ lọpọlọpọ,òpin ti dé bá ọ,okùn tí ó so ayé rẹ rọ̀ ti já. +OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra,pé òun yóo mú kí àwọn eniyan kún inú rẹ bí eṣú,wọn yóo sì kígbe ìṣé��gun lé ọ lórí. +OLUWA ni ó fi agbára rẹ̀ dá ilé ayé,tí ó fi ìdí ayé múlẹ̀ pẹlu ìmọ̀ rẹ̀,ó sì fi òye rẹ̀ ta àwọn ọ̀run bí aṣọ. +Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀,ojú ọ̀run yóo kún fún alagbalúgbú omi,ó sì ń mú ìkùukùu gòkè láti òpin ilẹ̀ ayé.Ó dá mànàmáná fún òjò,ó sì mú ìjì jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀. +Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan, wọn kò sì ní ìmọ̀,gbogbo alágbẹ̀dẹ wúrà sì gba ìtìjú lórí oriṣa tí wọn dà;nítorí pé irọ́ ni ère tí wọ́n rọ,wọn kò ní èémí. +Asán ni wọ́n, wọ́n ń ṣini lọ́nà,píparun ni wọn yóo parun, ní ọjọ́ ìjìyà wọn. +Ọlọrun ti Jakọbu kò dàbí àwọn wọnyi,nítorí pé òun ní ẹlẹ́dàá ohun gbogbo;ẹ̀yà Israẹli ni eniyan tirẹ̀,OLUWA àwọn ọmọ ogun sì ni orúkọ rẹ̀.OLUWA sọ fún Babiloni pé, +n óo rán ìjì líle kan sí Babiloni,ìjì náà yóo fẹ́ ẹ dànù bí ìyàngbò ọkàyóo sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro,nígbà tí wọ́n bá gbógun tì í yípo, ní ọjọ́ ìpọ́njú. +“Ìwọ ni òòlù ati ohun ìjà mi:ìwọ ni mo fi wó àwọn orílẹ̀-èdè wómúwómú,ìwọ ni mo sì fi pa àwọn ìjọba run. +Ìwọ ni mo fi lu ẹṣin ati ẹni tí ń gùn ún pa;ìwọ ni mo fi wó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn tí ń bẹ ninu wọn. +Ìwọ ni mo fi lu tọkunrin tobinrin pa,ìwọ ni mo fi lu tọmọde, tàgbà pa,ìwọ ni mo sì fi run àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin. +Ìwọ ni mo fi pa olùṣọ́-aguntan ati agbo ẹran rẹ̀ rẹ́,ìwọ ni mo fi run àgbẹ̀ ati àwọn alágbàro rẹ̀,ìwọ ni mo fi ṣẹ́ apá àwọn gomina ati ti àwọn olórí ogun.” +OLUWA ní,“Níṣojú yín ni n óo fi san ẹ̀san fún Babiloni,ati gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Kalidea,fún gbogbo ibi tí wọ́n ṣe sí Sioni;èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Wò ó! Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè ìparun,tí ò ń pa gbogbo ayé run.N óo gbá ọ mú, n óo tì ọ́ lulẹ̀ láti orí àpáta,n óo sì sọ ọ́ di òkè tí ó jóná. +Wọn kò ní rí òkúta kan mú jáde ninu rẹ,tí eniyan lè fi ṣe òkúta igun ilé;tabi tí wọn lè fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé,ń ṣe ni o óo wó lulẹ̀ títí ayé.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Ẹ ta àsíá sórí ilẹ̀ ayé,ẹ fun fèrè ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í,ẹ sì pe àwọn ìjọba jọ láti dojú kọ ọ́;àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè bíi Ararati, Minni, ati Aṣikenasi.Ẹ yan balogun tí yóo gbógun tì í;ẹ kó ẹṣin wá, kí wọn pọ̀ bí eṣú. +Kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í,kí àwọn ọba ilẹ̀ Media múra, pẹlu àwọn gomina wọn,ati àwọn ẹmẹ̀wà wọn,ati gbogbo ilẹ̀ tí ó wà lábẹ́ wọn. +Jìnnìjìnnì bo gbogbo ilẹ̀ náà,wọ́n wà ninu ìrora,nítorí pé OLUWA kò yí ìpinnu rẹ̀ lórí Babiloni pada,láti sọ ilẹ̀ náà di ahoro,láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀ mọ́. +Kí tafàtafà má kẹ́ ọrun rẹ̀,kí ó má sì gbé ẹ̀wù irin rẹ̀ wọ̀.Má ṣe dá àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ sí,pa gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ run patapata. +Àwọn ọmọ ogun Babiloni ti ṣíwọ́ ogun jíjà,wọ́n wà ní ibi ààbò wọn;àárẹ̀ ti mú wọn, wọ́n sì ti di obinrin.Àwọn ilé inú rẹ̀ ti ń jóná,àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ sì ti ṣẹ́. +Àwọn tí ń sáré ń pàdé ara wọn lọ́nà,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ikọ̀ ń pàdé ara wọn,bí wọ́n ti ń sáré lọ sọ fún ọba Babiloni pé ogun ti gba ìlú rẹ̀ patapata. +Wọ́n ti gba ibi ìsọdá odò,wọ́n ti dáná sun àwọn ibi ààbò,ìbẹ̀rùbojo sì ti mú àwọn ọmọ ogun. +Babiloni dàbí ibi ìpakà, tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ nígbà tí à ń pa ọkà.Láìpẹ́ ọ̀tá yóo dà á wó, yóo sì di àtẹ̀mọ́lẹ̀.Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Nebukadinesari ọba Babiloni ti run Jerusalẹmu,ó ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,ó ti sọ ọ́ di ohun èlò òfìfo,ó gbé e mì bí erinmi,ó ti kó gbogbo ohun àdídùn inú rẹ̀ jẹ ní àjẹrankùn,ó ti da ìyókù nù. +Jẹ́ kí àwọn tí ń gbé Sioni wí pé,‘Kí ibi tí àwọn ará Babiloni ṣe sí wa ati sí àwọn arakunrin wa dà lé wọn lórí.’Kí àwọn ará Jerusalẹmu sì wí pé,‘Ẹ̀jẹ̀ wa ń bẹ lórí àwọn ará ilẹ̀ Kalidea.’ ” +Nítorí náà, OLUWA sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé,“Ẹ wò ó, n óo gba ẹjọ́ yín rò,n óo sì ba yín gbẹ̀san.N óo jẹ́ kí omi òkun Babiloni gbẹ,n óo sì jẹ́ kí orísun odò rẹ̀ gbẹ. +Babiloni yóo sì di òkítì àlàpà, ati ibùgbé ajáko,yóo di ibi àríbẹ̀rù ati àrípòṣé, láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀. +Gbogbo wọn yóo bú papọ̀ bíi kinniun,wọn yóo sì ké bí àwọn ọmọ kinniun. +Nígbà tí ara wọn bá gbóná,n óo se àsè kan fún wọn.N óo rọ wọ́n lọ́tí yó,títí tí wọn óo fi máa yọ ayò�� ẹ̀sín,tí wọn óo sì sùn lọ títí ayé.Wọn óo sùn, wọn kò sì ní jí mọ́.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Kí wọ́n ṣubú, kí wọ́n sì kú ní ilẹ̀ Kalidea,kí wọ́n gún wọn ní àgúnyọ láàrin ìgboro. +N óo fà wọ́n lọ sí ibi tí wọn tí ń pa ẹran,bí ọ̀dọ́ aguntan, ati àgbò ati òbúkọ.” +OLUWA ní,“Ẹ wò ó bí ogun ti kó Babiloni,Babiloni tí gbogbo ayé ń pọ́nlé!Ó wá di àríbẹ̀rù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè! +Òkun ti ru bo Babiloni mọ́lẹ̀.Ìgbì òkun ti bò ó mọ́lẹ̀. +Àwọn ìlú rẹ̀ ti di àríbẹ̀rù,wọ́n ti di ilẹ̀ gbígbẹ ati aṣálẹ̀,ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé mọ́,tí ọmọ eniyan kò sì gbà kọjá mọ́. +N óo fìyà jẹ oriṣa Bẹli ní Babiloni,n óo jẹ́ kí ó pọ ohun tí ó gbé mì.Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́,odi Babiloni pàápàá yóo wó lulẹ̀. +“Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ jáde kúrò níbẹ̀!Kí olukuluku sá àsálà, kúrò lọ́wọ́ ibinu gbígbóná OLUWA! +Ẹ mọ́kàn, ẹ má bẹ̀rù,nítorí ìròyìn tí ẹ̀ ń gbọ́ nípa ilẹ̀ náà,nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìròyìn kan ní ọdún yìí,tí ẹ tún gbọ́ òmíràn ní ọdún tí ń bọ̀,tí ìwà ipá sì wà ní ilẹ̀ náà,tí àwọn ìjòyè sì ń dojú ìjà kọ ara wọn. +Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀tí n óo fìyà jẹ àwọn ère ilẹ̀ Babiloni.Ojú yóo ti gbogbo ilẹ̀ rẹ̀,òkú àwọn eniyan rẹ̀ tí ogun yóo pa,yóo wà nílẹ̀ káàkiri ìgboro. +Nítorí náà, ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn,yóo yọ̀ nítorí ìṣubú Babiloni,nítorí pé apanirun yóo wá gbógun tì í, láti ìhà àríwá,Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Bí àwọn tí ogun Babiloni pa ní àwọn orílẹ̀-èdè ayé,ti ṣubú níwájú rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni Babiloni náà gbọdọ̀ ṣubú,nítorí àwọn tí wọ́n pa ní Israẹli.” +Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ati Juda kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀;ṣugbọn ilẹ̀ Kalidea kún fún ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀,tí wọ́n dá sí Ẹni Mímọ́ Israẹli. +OLUWA sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ ní Babiloni pé,“Ẹ̀yin tí ẹ bọ́ lọ́wọ́ idà,ẹ má dúró, ẹ máa sálọ!Ẹ ranti OLUWA ní ilẹ̀ òkèèrè,kí ẹ sì máa ronú nípa Jerusalẹmu pẹlu. +Ẹ̀ ń sọ pé ojú ń tì yín nítorí pé wọ́n kẹ́gàn yín;ẹ ní ìtìjú dà bò yín,nítorí pé àwọn àjèjì ti wọ ibi mímọ́ ilé OLUWA. +Nítorí náà, èmi OLUWA ń sọ nisinsinyii pé,ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ère rẹ̀;àwọn tí wọ́n fara gbọgbẹ́ yóo máa kérora,ní gbogbo ilẹ̀ rẹ̀. +Bí Babiloni tilẹ̀ ga tí ó kan ojú ọ̀run,tí ó sì mọ odi yí àwọn ibi ààbò rẹ̀ gíga ká,sibẹsibẹ n óo rán apanirun sí i.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA ní,“Ẹ gbọ́ igbe kan láti Babiloni!Igbe ìparun ńlá láti ilẹ̀ àwọn ará Kalidea! +Nítorí OLUWA ń wó Babiloni lulẹ̀,ó sì ń pa á lẹ́nu mọ́.Igbe wọn ta sókè bíi híhó omi òkun ńlá +nítorí pé apanirun ti dé sí i,àní ó ti dé sí Babiloni.Ogun ti kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀,àwọn ọ̀tá ti rún àwọn ọfà rẹ̀ jégéjégé,nítorí pé Ọlọrun ẹ̀san ni èmi OLUWA,dájúdájú n óo gbẹ̀san. +N óo jẹ́ kí àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ mu ọtí ní àmuyó,pẹlu àwọn gomina rẹ̀, àwọn ọ̀gágun rẹ̀, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀.Wọn yóo sun oorun àsùnrayè,wọn kò sì ní jí mọ́ laelae.Bẹ́ẹ̀ ni èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ. +Odi Babiloni tí ó fẹ̀, yóo wó lulẹ̀,a óo sì dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀ tí ó ga fíofío.Iṣẹ́ lásán ni àwọn eniyan ń ṣe,àwọn orílẹ̀-èdè sì ń yọ ara wọn lẹ́nu lásán ni,nítorí pé iná yóo jó gbogbo làálàá wọn.” +Jeremaya wolii pa àṣẹ kan fún Seraaya, alabojuto ibùdó ogun, ọmọ Neraya, ọmọ Mahiseaya nígbà tí ó ń bá Sedekaya ọba Juda lọ sí Babiloni ní ọdún kẹrin ìjọba Sedekaya. +Ẹ sá kúrò láàrin Babiloni,kí olukuluku sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀!Ẹ má parun nítorí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ Babiloni;nítorí àkókò ẹ̀san OLUWA nìyí,yóo sì san ẹ̀san fún Babiloni. +Jeremaya kọ gbogbo nǹkan burúkú tí yóo ṣẹlẹ̀ sí Babiloni ati gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ nípa rẹ̀ sinu ìwé kan. +Ó bá pàṣẹ fún Seraaya pé nígbà tí ó bá dé Babiloni, kí ó rí i dájú pé ó ka gbogbo ohun tí òun kọ sinu ìwé náà sókè. +Kí ó sọ pé, “OLUWA, o ti sọ pé o óo pa ibí yìí run, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí nǹkankan tí yóo máa gbé inú rẹ̀ mọ́, ìbáà ṣe eniyan tabi ẹranko. O ní títí lae ni yóo di ahoro.” +Jeremaya ní nígbà tí Seraaya bá ka ìwé yìí tán, kí ó di òkúta kan mọ́ ọn kí ó jù ú sí ààrin odò Yufurate, +kí ó sì sọ wí pé, “Báyìí ni yóo rí fún Babiloni, kò sì ní gbérí mọ́, nítorí ibi tí OLUWA yóo mú kí ó dé bá a.” Ibí yìí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremaya sọ parí sí. +Ife wúrà ni Babiloni jẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ó ń pa gbogbo ayé bí ọtí;àwọn orílẹ̀-èdè mu ninu ọtí rẹ̀,wọ́n sì ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n. +Babiloni ṣubú lójijì, ó sì fọ́;ẹ sun ẹkún arò nítorí rẹ̀!Ẹ fi ìwọ̀ra pa á lára nítorí ìrora rẹ̀,bóyá ara rẹ̀ yóo yá. +À bá wo Babiloni sàn, ṣugbọn a kò rí i wòsàn.Ẹ pa á tì, ẹ jẹ́ kí á lọ,kí olukuluku máa lọ sí ilẹ̀ rẹ̀;nítorí ẹjọ́ tí a dá a ti dé òkè ọ̀run,a sì ti gbé e sókè dé ojú ọ̀run.” +Ìṣubú Jerusalẹmu. +Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó jọba, ọdún mọkanla ni ó sì fi wà lórí oyè ní Jerusalẹmu. Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina ni ìyá rẹ̀. +Ọba Babiloni pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, ó sì pa àwọn ìjòyè Juda ní Ribila. +Ó yọ ojú Sedekaya mejeeji, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó mú un lọ sí Babiloni, ó sì jù ú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, títí tí ó fi kú. +Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ní ọdún kọkandinlogun tí Nebukadinesari ọba Babiloni jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, wọ ìlú Jerusalẹmu. +Ó sun ilé OLUWA níná ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu; gbogbo àwọn ilé ńláńlá ní ó dáná sun. +Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí ń ṣọ́ Nebukadinesari ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata. +Nebusaradani, olórí àwọn olùṣọ́ ọba bá kó ninu àwọn talaka lẹ́rú pẹlu àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ìlú, ati àwọn tí wọ́n ti sálọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni, ati àwọn oníṣẹ́-ọwọ́. +Ṣugbọn ó ṣẹ́ àwọn díẹ̀ kù sílẹ̀ ninu àwọn talaka pé kí wọn máa ṣe ìtọ́jú ọgbà àjàrà kí wọn sì máa dá oko. +Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada omi tí ó wà níbẹ̀ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Gbogbo rẹ̀ ni wọ́n fọ́ tí wọn rún wómúwómú; wọ́n sì kó gbogbo bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí Babiloni. +Bákan náà ni wọ́n kó àwọn ìkòkò, ọkọ́, ati àwọn ọ̀pá tí wọn fi ń pa iná ẹnu àtùpà; àwọn àwokòtò, àwọn àwo turari, ati gbogbo àwọn ohun-èlò tí wọ́n fi bàbà ṣe, tí wọn ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA. +Wọ́n sì kó àwọn abọ́ kéékèèké, àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwokòtò; àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀pá fìtílà, ati àwọn àwo turari, ati àwọn abọ́ tí wọ́n fi ń ta ohun mímu sílẹ̀. Gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe ni Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ. +Sedekaya ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, bí Jehoiakimu ti ṣe. +Bàbà tí Solomoni fi ṣe òpó mejeeji ati agbada omi, pẹlu àwọn mààlúù idẹ mejeejila tí wọ́n gbé agbada náà dúró, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé OLUWA kọjá wíwọ̀n. +Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn òpó náà ga ní igbọnwọ mejidinlogun, àyíká wọn jẹ́ igbọnwọ mejila, wọ́n nípọn, ní ìka mẹrin, wọ́n sì ní ihò ninu. +Ọpọ́n idẹ orí rẹ̀ ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati èso Pomegiranate yí ọpọ́n náà ká. +Òpó keji rí bákan náà pẹlu èso Pomegiranate. Mẹrindinlọgọrun-un ni àwọn èso Pomegiranate tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan; ọgọrun-un ni gbogbo èso Pomegiranate tí ó wà ní àyíká ẹ̀wọ̀n náà. +Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraaya, olórí alufaa ati Sefanaya tí ó jẹ́ igbákejì rẹ̀ ati àwọn aṣọ́nà mẹtẹẹta. +Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun, ati meje ninu àwọn aṣojú ọba tí wọn rí láàrin ìlú ati akọ̀wé olórí ogun tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀ fún ogun jíjà. Wọ́n tún kó ọgọta eniyan ninu àwọn ará ìlú tí wọn rí láàrin ìgboro. +Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó wọn lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila. +Ọba Babiloni sì pa wọ́n ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati.Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe kó àwọn eniyan Juda ní ìgbèkùn kúrò ní ilẹ̀ wọn. +Iye àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó lọ sí ìgbèkùn nìwọ̀nyí ní ọdún keje tí ó jọba, ó kó ẹgbẹẹdogun ó lé mẹtalelogun (3,023) lára àwọn Juu. +Ní ọdún kejidinlogun, ó kó àwọn ẹgbẹrin ó lé mejilelọgbọn (832) eniyan ní Jerusalẹmu. +Nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ ní Jerusalẹmu ati Juda burú débi pé inú fi bí OLUWA sí wọn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi tì wọ́n jáde kúrò níwájú rẹ̀.Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni. +Ní ọdún kẹtalelogun tí Nebukadinesari jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ��ọ́ ọba, kó ojilelẹẹdẹgbẹrin ó lé marun-un (745) eniyan lára àwọn Juu. Gbogbo àwọn eniyan tí wọn kó lẹ́rú jẹ́ ẹgbaaji lé ẹgbẹta (4,600). +Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí a ti mú Jehoiakini, ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù kejila ọdún náà Efilimerodaki, ọba Babiloni yẹ ọ̀rọ̀ Jehoiakini wò ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí á tú u sílẹ̀ kúrò ní àtìmọ́lé. +Ó bá a sọ ọ̀rọ̀ rere, ó sì fi sí ipò tí ó ga jùlọ, àní ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Babiloni lọ. +Jehoiakini bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n kúrò lọ́rùn, ó sì ń bá ọba jẹun lórí tabili ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. +Ọba Babiloni sì rí i pé òun ń pèsè gbogbo ohun tí ó nílò lojoojumọ fún un títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. +Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa, ní ọdún kẹsan-an tí Sedekaya gorí oyè, Nebukadinesari, ọba Babiloni, dé sí Jerusalẹmu pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ yíká. +Wọ́n dóti ìlú náà títí di ọdún kọkanla ìjọba Sedekaya. +Ní ọjọ́ kẹsan-an oṣù kẹrin, ìyàn mú ní ààrin ìlú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará ìlú kò fi rí oúnjẹ jẹ mọ́. +Wọ́n lu odi ìlú, àwọn ọmọ ogun sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin àwọn odi meji tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n bá dorí kọ apá ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani. +Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa ọba Sedekaya, wọ́n sì bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá fọ́nká lẹ́yìn rẹ̀. +Ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Kalidea tẹ Sedekaya ọba, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babiloni sì ṣe ìdájọ́ fún un. +Àwọn Ọ̀tá Yí Jerusalẹmu Ká. +Ẹ̀yin ọmọ Bẹnjamini, ẹ sá àsálà!Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu.Ẹ fọn fèrè ogun ní Tekoa,kí ẹ ṣe ìkìlọ̀ fún wọn ní Beti Hakikeremu,nítorí pé nǹkan burúkúati ìparun ńlá ń bọ̀ láti ìhà àríwá. +Mo ní, “Ta ni kí n bá sọ̀rọ̀, tí yóo gbọ́?Ta ni kí n kìlọ̀ fún tí yóo gbà?Etí wọn ti di, wọn kò lè gbọ́ràn mọ́.Ọ̀rọ̀ OLUWA ń rùn létí wọn,wọn kò fẹ́ gbọ́ mọ́. +Ibinu ìwọ OLUWA mú kí inú mi máa ru,ara mi kò sì gbà á mọ́.”OLUWA bá sọ fún mi pé,“Tú ibinu mi dà sórí àwọn ọmọde ní ìta gbangba,ati àwọn ọdọmọkunrin níbi tí wọ́n péjọ sí.Ogun yóo kó wọn, tọkọtaya,àtàwọn àgbàlagbà àtàwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́. +Ilé wọn yóo di ilé onílé,oko wọn, ati àwọn aya wọn pẹlu, yóo di ti ẹni ẹlẹ́ni.Nítorí pé n óo na ọwọ́ ibinu mi sí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA ní, “Láti orí àwọn mẹ̀kúnnù títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki,gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn èrè àjẹjù;láti orí àwọn wolii títí dé orí àwọn alufaa,èké ni gbogbo wọn. +Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jiná, wọ́n ń kígbe pé: ‘Alaafia ni, alaafia ni’,nígbà tí kò sí alaafia. +Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́? Rárá o, ojú kì í tì wọ́n; nítorí pé wọn kò lójútì.Nítorí náà, àwọn náà óo ṣubú nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú,a ó bì wọ́n ṣubú nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà,Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA ní,“Ẹ lọ dúró ní oríta kí ẹ wo òréré,ẹ bèèrè àwọn ọ̀nà àtijọ́,níbi tí ọ̀nà dáradára wà, kí ẹ sì máa tọ̀ ọ́.Kí ẹ lè ní ìsinmi.”Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọ́n ní,“A kò ní tọ ọ̀nà náà.” +Mo fi àwọn aṣọ́nà ṣọ́nà nítorí yín.Mo wí fún wọn pé,“Ẹ máa dẹtí sílẹ̀ sí fèrè ogun!”Ṣugbọn wọ́n ní, “A kò ní dẹtí sílẹ̀.” +OLUWA ní, “Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,kí ẹ̀yin eniyan sì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn. +Gbọ́! Ìwọ ilẹ̀;n óo fa ibi lé àwọn eniyan wọnyi lórí,wọn óo jèrè èso ìwà burúkú wọn;nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi,wọ́n sì ti tàpá sí òfin mi. +Jerusalẹmu, Ìlú Sioni dára, ó sì lẹ́wà,ṣugbọn n óo pa á run. +Kí ni anfaani turari,tí wọn mú wá fún mi láti Ṣeba,tabi ti ọ̀pá turari olóòórùn dídùn tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè wá?N kò tẹ́wọ́ gba ọrẹ ẹbọ sísun tí ẹ mú wá siwaju mi,bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ yín kò dùn mọ́ mi. +Nítorí náà, n óo gbé ohun ìdínà sọ́nà fún àwọn eniyan wọnyi,wọn óo sì fẹsẹ̀ kọ;ati baba, àtọmọ wọn,àtaládùúgbò, àtọ̀rẹ́,gbogbo wọn ni yóo parun.” +OLUWA ní,“Wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,orílẹ̀-èdè ńlá ń gbéra bọ̀ láti òpin ayé. +Wọ́n ń kó ọrun ati ọ̀kọ̀ bọ̀,ìkà ni wọ́n, wọn kò sì lójú àánú.Ìró wọn dàbí híhó omi òkun,bí wọ́n ti ń gun ẹṣin bọ̀.Wọ́n tò bí àwọn tí ń lọ sójú ogun,wọ́n dótì ọ́, ìwọ Jerusalẹmu!” +A gbúròó wọn, ọwọ́ wa rọ;ìdààmú dé bá wa,bí ìrora obinrin tí ó ń rọbí. +Ẹ má lọ sinu oko,ẹ má sì ṣe rìn lójú ọ̀nà náà,nítorí ọ̀tá mú idà lọ́wọ́,ìdágìrì sì wà káàkiri. +Ẹ̀yin eniyan mi,ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ máa yí ninu eérú;ẹ máa ṣọ̀fọ̀, bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo;kí ẹ sì máa sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóo bò yín. +Mo ti fi ọ́ ṣe ẹni tí yóo máa dán àwọn eniyan mi wò,o óo máa dán wọn wò bí ẹni dán irin wò,o óo gbìyànjú láti mọ ọ̀nà wọn,kí o lè yẹ ọ̀nà wọn wò, kí o sì mọ̀ ọ́n. +Ọlọ̀tẹ̀, aláìgbọràn ni gbogbo wọn,wọn á máa sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn.Wọ́n dàbí idẹ àdàlú mọ́ irin,àmúlùmálà ni gbogbo wọn. +Lóòótọ́ à ń fi ẹwìrì fẹ́ iná,òjé sì ń yọ́ lórí iná;ṣugbọn alágbẹ̀dẹ ń yọ́ irin lásán ni,kò mú ìbàjẹ́ ara rẹ̀ kúrò. +Àwọn ọba ati àwọn ọmọ ogun wọn yóo kọlù ú,wọn yóo pa àgọ́ yí i ká,ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan yóo pàgọ́ sí ibi tí ó wù ú. +Ìdọ̀tí fadaka tí a kọ̀ tì ni wọ́n,nítorí pé OLUWA ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀. +Wọn yóo sì wí pé, “Ẹ múra kí á bá a jagun;ẹ dìde kí á lè kọlù ú lọ́sàn-án gangan!”Wọn óo tún sọ pé, “A gbé! Nítorí pé ọjọ́ ti lọ,ilẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣú! +Ẹ dìde kí á lè kọlù ú, lóru;kí á wó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀!” +Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀tá pé:“Ẹ gé àwọn igi tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀;kí ẹ fi mọ òkítì kí ẹ sì dótì í.Dandan ni kí n fi ìyà jẹ ìlú náà,nítorí kìkì ìwà ìninilára ló kún inú rẹ̀. +Bí omi ṣé ń sun jáde ninu kànga,bẹ́ẹ̀ ni ibi ń sun ní Jerusalẹmu.Ìròyìn ìwà ipá ati ti jàgídíjàgan ń kọlura wọn ninu rẹ̀,àìsàn ati ìpalára ni à ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo. +Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ tí mò ń ṣe fun yín,bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi pẹlu yín óo pínyà,n óo sì sọ Jerusalẹmu di ahoro,ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé ibẹ̀ mọ́.” +OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:“Ẹ ṣa àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ,bí ìgbà tí eniyan bá ń ṣa èso àjàrà tókù lẹ́yìn ìkórè.Tún dá ọwọ́ pada sẹ́yìn, kí o fi wọ́ ara àwọn ẹ̀ka,bí ẹni tí ń ká èso àjàrà.” +Jeremaya Waasu ninu Tẹmpili. +OLUWA rán Jeremaya níṣẹ́, ó ní +kí ẹ sì tún máa wá jọ́sìn níwájú mi ninu ilé yìí, ilé tí à ń fi orúkọ mi pè; kí ẹ máa wí pé, “OLUWA ti gbà wá là;” kí ẹ sì tún pada lọ máa ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí ẹ tí ń ṣe? +Ṣé lójú tiyín, ilé yìí, tí à ń fi orúkọ mi pè, ó ti wá di ibi ìsápamọ́ sí fún àwọn olè? Mo ti ri yín; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Nisinsinyii, ẹ lọ sí ilé mi ní Ṣilo, níbi ìjọ́sìn mi àkọ́kọ́, kí ẹ sì wo ohun tí mo ṣe sí i, nítorí ìwà burúkú Israẹli, àwọn eniyan mi. +Nisinsinyii, nítorí gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe wọnyi, tí mo sì ń ba yín sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́, tí ẹ kò gbọ́, tí mo pè yín, tí ẹ kò dáhùn, +bí mo ti ṣe sí Ṣilo ni n óo ṣe ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, tí ẹ gbójú lé; ati ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +N óo le yín kúrò níwájú mi, bí mo ti lé àwọn ọmọ Efuraimu, tí wọ́n jẹ́ arakunrin yín dànù.’ ” +OLUWA ní, “Ìwọ Jeremaya ní tìrẹ, má bẹ̀bẹ̀ fún àwọn eniyan wọnyi, má sọkún nítorí wọn, tabi kí o gbadura fún wọn. Má sì bẹ̀ mí nítorí wọn, nítorí n kò ní gbọ́. +Ṣé o kò rí àwọn ohun tí wọn ń ṣe ninu àwọn ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu ni? +Àwọn ọmọ ń kó igi jọ, àwọn baba wọn ń dá iná, àwọn obinrin ń po ìyẹ̀fun láti fi ṣe àkàrà fún Ayaba Ọ̀run. Wọ́n sì ń ta ọtí sílẹ̀ fún àwọn oriṣa láti mú mi bínú. +Ṣé èmi ni wọ́n ń mú bínú? Kì í ṣe pé ara wọn ni wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì ń dójú ti ara wọn? +kí Jeremaya dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, kí ó sì kéde pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ń gba ẹnu ọ̀nà wọnyi wọlé láti sin OLUWA. +Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun óo tú ibinu gbígbóná mi sórí ibí yìí, n óo bínú sí eniyan ati ẹranko, ati igi oko ati èso ilẹ̀. Ibinu mi óo jó wọn run bí iná, kò sì ní ṣe é pa. +“Ẹ da ẹbọ sísun yín pọ̀ mọ́ ���ran tí ẹ fi rúbọ, kí ẹ lè rí ẹran jẹ; Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Nítorí ní ọjọ́ tí mo kó àwọn baba yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, n kò bá wọn sọ̀rọ̀ ẹbọ sísun tabi ẹbọ rírú, bẹ́ẹ̀ ni n kò pàṣẹ rẹ̀ fún wọn. +Àṣẹ tí mo pa fún wọn ni pé kí wọn gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Mo ní n óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà óo sì máa jẹ́ eniyan mi; mo ní kí wọn máa tọ ọ̀nà tí mo bá pa láṣẹ fún wọn, kí ó lè dára fún wọn. +Ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọn kò sì tẹ́tí sí mi. Wọ́n ń tẹ̀lé ìmọ̀ ara wọn, wọ́n ń ṣe oríkunkun, dípò kí wọ́n máa lọ siwaju, ẹ̀yìn ni wọ́n ń pada sí. +Láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní ilẹ̀ Ijipti títí di òní, lojoojumọ ni mò ń rán àwọn wolii iranṣẹ mi sí wọn léraléra. +Sibẹ wọn kò gbọ́ tèmi, wọn kò tẹ́tí sí mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, oríkunkun ni wọ́n ń ṣe. Iṣẹ́ burúkú wọn ju ti àwọn baba ńlá wọn lọ. +“Gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ni o óo sọ fún wọn, ṣugbọn wọn kò ní gbọ́. O óo pè wọ́n, ṣugbọn wọn kò ní dá ọ lóhùn. +O óo sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ̀, tí kò sì gbọ́ ìbáwí. Òtítọ́ kò sí mọ́ ninu ìṣe yín, bẹ́ẹ̀ ni, kò sì sí ninu ọ̀rọ̀ ẹnu yín.’ +“Ẹ gé irun orí yín dànù,ẹ lọ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí òkè,nítorí OLUWA ti kọ ìran yín sílẹ̀,ó ti fi ibinu ta ìran yín nù. +OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: ‘Ẹ tún ìrìn ẹsẹ̀ yín ati iṣẹ́ ọwọ́ yín ṣe, kí n lè jẹ́ kí ẹ máa gbé ìhín. +“Àwọn ọmọ Juda ti ṣe nǹkan burúkú. Wọ́n gbé ère wọn kalẹ̀ ninu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, wọ́n sì ti sọ ọ́ di aláìmọ́. +Wọ́n kọ́ pẹpẹ Tofeti ní àfonífojì Hinomu, wọ́n ń sun àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin wọn níná níbẹ̀. N kò pa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún wọn; irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ fi ìgbà kan sí lọ́kàn mi. +Nítorí náà nígbà tó bá yá, a kò ní pè é ní Tofeti tabi àfonífojì ọmọ Hinomu mọ́, àfonífojì ìpànìyàn ni a óo sì máa pè é. Tofeti ni wọn yóo sì máa sin òkú sí nígbà tí kò bá sí ààyè ní ibòmíràn mọ́. +Òkú àwọn eniyan yìí yóo di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati fún àwọn ẹranko, kò sì ní sí ẹni tí yóo lé wọn. +N óo fi òpin sí ẹ̀rín ati ìró ayọ̀ ní Jerusalẹmu, a kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé níbẹ̀ mọ́; nítorí pé n óo sọ ilẹ̀ náà di ahoro. +Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn yìí pé: “Tẹmpili OLUWA nìyí, kò séwu, tẹmpili OLUWA nìyí.” +“ ‘Bí ẹ bá tún ìrìn ẹsẹ̀ yín ati iṣẹ́ ọwọ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ bá ń dá ẹjọ́ òtítọ́, +tí ẹ kò bá fi ìyà jẹ àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, tabi àwọn opó, tabi kí ẹ máa ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, tí ẹ kò sì máa bọ oriṣa káàkiri, kí ẹ fi kó bá ara yín, +n óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí títí lae, lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín láti ìgbà laelae. +“ ‘Ẹ wò ó! Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò lè mú èrè wá ni ẹ gbójú lé. +Ṣé ẹ fẹ́ máa jalè, kí ẹ máa pa eniyan, kí ẹ máa ṣe àgbèrè, kí ẹ máa búra èké, kí ẹ máa sun turari sí oriṣa Baali, kí ẹ máa bọ àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ káàkiri; +Ẹ̀ṣẹ̀ ati Ìjìyà. +“Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo kó egungun àwọn ọba Juda jáde kúrò ninu ibojì wọn, ati egungun àwọn ìjòyè ibẹ̀; ati ti àwọn alufaa, ati ti àwọn wolii, ati ti àwọn ará Jerusalẹmu. +Nítorí náà, n óo fi aya wọn fún ẹlòmíràn,n óo fi oko wọn fún àwọn tí yóo ṣẹgun wọn.Nítorí pé láti orí àwọn mẹ̀kúnnù,títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki,gbogbo wọn ni wọ́n ń lépa èrè àjẹjù.Láti orí wolii títí kan alufaa, èké ni gbogbo wọn. +Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jinná, wọ́n ń kígbe pé, ‘Alaafia ni, alaafia ni,’bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí alaafia. +Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́?Rárá o, ojú kì í tì wọ́n,nítorí pé wọn kò lójútì.Nítorí náà àwọn náà óo ṣubúnígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú,a óo bì wọ́n ṣubúnígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà,OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +“Ní àkókò ìkórè, kò ní sí èso lórí àjàrà,igi ọ̀pọ̀tọ́ kò ní ní èso lórí,àwọn ewé pàápàá yóo gbẹ,ohun tí mo fún wọn yóo di ti ẹlòmíràn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Àwọn eniyan Ọlọrun bá dáhùn pé,“Kí ló dé tí a fi jókòó jẹ̀kẹ̀tẹ̀?Ẹ jẹ́ kí á kó ara wa jọ,k�� á sá lọ sí àwọn ìlú olódi,kí á sì parun sibẹ;nítorí OLUWA Ọlọrun wa ti fi wá lé ìparun lọ́wọ́,ó ti fún wa ní omi tí ó ní májèlé mu,nítorí pé a ti ṣẹ̀ ẹ́. +À ń retí alaafia,ṣugbọn ire kankan kò dé.Àkókò ìwòsàn ni à ń retí,ṣugbọn ìpayà ni a rí. +Ẹ gbọ́ bí ẹṣin wọn tí ń fọn imú, ní ilẹ̀ Dani;gbogbo ilẹ̀ ń mì tìtì nítorí ìró yíyan ẹṣin wọn.Wọ́n wá run ilẹ̀ náà,ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,ati ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.” +OLUWA ní, “Wò ó! N óo rán ejò sí ààrin yín:paramọ́lẹ̀ tí kò ní gbóògùn;wọn yóo sì bù yín jẹ.” +Ìbànújẹ́ mi pọ̀ kọjá ohun tí ó ṣe é wòsàn,àárẹ̀ mú ọkàn mi. +Ẹ gbọ́ igbe àwọn eniyan mijákèjádò ilẹ̀ náà tí wọn ń bèèrè pé,“Ṣé OLUWA kò sí ní Sioni ni?Tabi ọba rẹ̀ kò sí ninu rẹ̀ ni?”OLUWA, ọba wọn dáhùn pé,“Kí ló dé tí wọn ń fi ère wọn mú mi bínú,pẹlu àwọn oriṣa ilẹ̀ àjèjì tí wọn ń bọ?” +Wọn óo fọ́n wọn dà sílẹ̀ ninu oòrùn, ati lábẹ́ òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n ní ìfẹ́ sí, tí wọ́n sì sìn; àwọn ohun tí wọn ń wá kiri, tí wọn ń ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń bọ. A kò ní kó egungun wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní sin wọ́n. Wọn óo dàbí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí ilẹ̀. +Àwọn eniyan ní, “Ìkórè ti parí,àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn ti kọjá,sibẹ a kò rí ìgbàlà.” +Nítorí ọgbẹ́ àwọn eniyan mi ni ọkàn mi ṣe gbọgbẹ́.Mò ń ṣọ̀fọ̀, ìdààmú sì bá mi. +Ṣé kò sí ìwọ̀ra ní Gileadi ni?Àbí kò sí oníwòsàn níbẹ̀?Kí ló dé tí àìsàn àwọn eniyan mi kò sàn? +Yóo sàn kí àwọn tí ó bá kù ninu ìran burúkú yìí kú ju kí wọ́n wà láàyè lọ, ní ibikíbi tí mo bá lé wọn lọ. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé,“Ṣé bí eniyan bá ṣubúkì í tún dìde mọ́?Àbí bí eniyan bá ṣìnà,kì í pada mọ́? +Kí ló dé tí àwọn eniyan wọnyi fi yipadakúrò lọ́dọ̀ mi,tí wọn ń lọ láì bojúwẹ̀yìn?Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ni wọ́n sì wawọ́ mọ́;wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi. +Mo tẹ́tí sílẹ̀ kí n gbọ́ tiwọn,ṣugbọn wọn kò sọ̀rọ̀ rere.Kò sí ẹni tí ó kẹ́dùn iṣẹ́ ibi rẹ̀,kí ó wí pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’Olukuluku tẹ̀ sí ọ̀nà tí ó wù ú,bí ẹṣin tí ń sáré lọ ojú ogun. +Ẹyẹ àkọ̀ tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá mọ àkókò rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ sì ni àdàbà, ati lékèélékèé, ati alápàáǹdẹ̀dẹ̀;wọ́n mọ àkókò tí ó yẹ láti ṣípò pada.Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò mọ òfin OLUWA. +Báwo ni ẹ ṣe lè wí pé,‘Ọlọ́gbọ́n ni wá,a sì mọ òfin OLUWA?’Ṣugbọn àwọn akọ̀wé ti fi gègé irọ́ wọn sọ ọ́ di èké. +Ojú yóo ti àwọn ọlọ́gbọ́n:ìdààmú yóo bá wọn,ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.Wò ó! Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀,ọgbọ́n wo ni ó kù tí wọ́n gbọ́n? +Àwọn Eniyan Jerusalẹmu kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́. +Orí mi ìbá jẹ́ kìkì omi,kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé;tọ̀sán-tòru ni ǹ bá fi máa sọkún,nítorí àwọn eniyan mi tí ogun ti pa. +Mo ní, “Gbé ẹnu sókè kí o sọkún nítorí àwọn òkè ńlá,sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn pápá inú aṣálẹ̀,nítorí gbogbo wọn ti di ahoro, láìsí ẹnìkan tí yóo la ààrin wọn kọjá.A kò ní gbọ́ ohùn ẹran ọ̀sìn níbẹ̀.Ati ẹyẹ, ati ẹranko, gbogbo wọn ti sá lọ.” +OLUWA ní, “N óo sọ Jerusalẹmu di àlàpà ati ibùgbé ajáko.N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoroẹnikẹ́ni kò ní gbé inú wọn mọ́.Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Mo bá bèèrè pé, “Ta ni ẹni tí ó gbọ́n, tí òye nǹkan yìí yé? Ta ni OLUWA ti bá sọ̀rọ̀, kí ó kéde rẹ̀? Kí ló dé tí ilẹ̀ náà fi parun, tí ó sì dàbí aṣálẹ̀ tóbẹ́ẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò fi gba ibẹ̀ kọjá?” +OLUWA bá dáhùn, ó ní, “Nítorí pé wọ́n kọ òfin tí mo gbékalẹ̀ fún wọn sílẹ̀, wọn kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, +ṣugbọn wọ́n ń fi agídí ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, bí àwọn baba wọn ti kọ́ wọn. +Nítorí náà, n óo fún wọn ní igi tí ó korò jẹ, n óo sì fún wọn ní omi tí ó ní májèlé mu. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +N óo fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ati àwọn baba ńlá wọn kò mọ̀, n óo sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ idà tẹ̀lé wọn títí tí n óo fi pa wọ́n run.” +OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:“Ẹ ronú sí ọ̀rọ̀ yìí kí ẹ pe àwọn obinrin tíí máa ń ṣọ̀fọ̀ wá,ẹ ranṣẹ pe àwọn obinrin tí wọ́n mọ ẹkún sun dáradára; +kí wọ́n wá kíá,kí wọ́n wá máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lé wa lórí,kí omi sì máa dà lójú wa pòròpòrò. +Nítorí a gbọ́ tí ẹkún sọ ní Sioni,wọ́n ń ké pé, ‘A gbé!Ìtìjú ńlá dé bá wa,a níláti kó jáde nílé,nítorí pé àwọn ọ̀tá ti wó ilé wa.’ ” +Ìbá ṣe pé mo ní ilé èrò kan ninu aṣálẹ̀,ǹ bá kó àwọn eniyan mi dà sílẹ̀ níbẹ̀,ǹ bá sì kúrò lọ́dọ̀ wọn;nítorí alágbèrè ni gbogbo wọn,ati àgbájọ àwọn alárèékérekè eniyan. +Mo ní, “Ẹ̀yin obinrin, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín obinrin ní ẹkún sísun,kí ẹ sì kọ́ aládùúgbò yín ní orin arò. +Nítorí ikú ti dé ojú fèrèsé wa,ó ti wọ ààfin wa.Ikú ń pa àwọn ọmọde nígboro,ati àwọn ọdọmọkunrin ní gbàgede.” +Sọ wí pé,“Òkú eniyan yóo sùn lọ nílẹ̀ bí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí pápá tí ó tẹ́jú,ati bíi ìtí ọkà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń kórè ọkà,kò sì ní sí ẹni tí yóo kó wọn jọ. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA ní, “Kí ọlọ́gbọ́n má fọ́nnu nítorí ọgbọ́n rẹ̀,kí alágbára má fọ́nnu nítorí agbára rẹ̀;kí ọlọ́rọ̀ má sì fọ́nnu nítorí ọrọ̀ rẹ̀. +Ṣugbọn ẹni tí ó bá fẹ́ fọ́nnu,ohun tí ó lè máa fi fọ́nnu ni pé òun ní òyeati pé òun mọ̀ pé, èmi OLUWA ni OLUWA tí ń ṣe ẹ̀tọ́,tí sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òdodo hàn lórí ilẹ̀ ayé;nítorí pé àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni mo ní inú dídùn sí.” +Ó ní, “Ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo fìyà jẹ àwọn tí a kọ nílà, ṣugbọn tí wọn ń ṣe bí aláìkọlà, +àwọn ará Ijipti, àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Amoni àwọn ará Moabu, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú aṣálẹ̀; tí wọn ń fá apá kan irun orí wọn; nítorí pé bí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò ṣe kọlà abẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli kò kọlà ọkàn.” +Bí ẹni kẹ́ ọrun ni wọ́n kẹ́ ahọ́n wọn,láti máa fọ́n irọ́ jáde bí ẹni ta ọfà;dípò òtítọ́ irọ́ ní ń gbilẹ̀ ní ilẹ̀ náà.OLUWA ní,“Wọ́n ń tinú ibi bọ́ sinu ibi,wọn kò sì mọ̀ èmi OLUWA.” +Kí olukuluku ṣọ́ra lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,kí ó má sì gbẹ́kẹ̀lé arakunrin rẹ̀ kankan.Nítorí pé ajinnilẹ́sẹ̀ ni gbogbo arakunrin,a-fọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ sì ni gbogbo aládùúgbò. +Olukuluku ń tan ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ,kò sì sí ẹnìkan tí ń sọ òtítọ́.Wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn ní irọ́ pípa;wọ́n dẹ́ṣẹ̀ títí, ó sú wọn,wọn kò sì ronú àtipàwàdà. +Ìninilára ń gorí ìninilára,ẹ̀tàn ń gorí ẹ̀tàn,OLUWA ní, “Wọ́n kọ̀ wọn kò mọ̀ mí.” +Nítorí náà, ó ní:“Wò ó! N óo fọ̀ wọ́n mọ́,n óo dán wọn wò.Àbí, kí ni kí n tún ṣe fún àwọn eniyan yìí? +Ahọ́n wọn dàbí ọfà apanirun,wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.Olukuluku ń sọ̀rọ̀ alaafia jáde lẹ́nu fún aládùúgbò rẹ̀,ṣugbọn ète ikú ni ó ń pa sí i ninu ọkàn rẹ̀. +Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?” +Ọlọrun di Eniyan. +Ní ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé, ni Ọ̀rọ̀ ti wà, Ọ̀rọ̀ wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun sì ni Ọ̀rọ̀ náà. +Ọ̀rọ̀ ti wà ninu ayé. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ayé, sibẹ ayé kò mọ̀ ọ́n. +Ó wá sí ìlú ara rẹ̀, ṣugbọn àwọn ará ilé rẹ̀ kò gbà á. +Ṣugbọn iye àwọn tí ó gbà á, ni ó fi àṣẹ fún láti di ọmọ Ọlọrun, àní àwọn tí ó gba orúkọ rẹ̀ gbọ́. +A kò bí wọn bí eniyan ṣe ń bímọ nípa ìfẹ́ ara tabi ìfẹ́ eniyan, ṣugbọn nípa ìfẹ́ Ọlọrun ni a bí wọn. +Ọ̀rọ̀ náà wá di eniyan, ó ń gbé ààrin wa, a rí ògo rẹ̀, ògo bíi ti Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́. +Johanu jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó ń ké rara pé, “Ẹni tí mo sọ nípa rẹ̀ nìyí pé, ‘Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi tí ó jù mí lọ, nítorí ó ti wà ṣiwaju mi.’ ” +Nítorí láti inú ẹ̀kún ibukun rẹ̀ ni gbogbo wa ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà kún oore-ọ̀fẹ́. +Nípasẹ̀ Mose ni a ti fún wa ní Òfin, ṣugbọn nípasẹ Jesu Kristi ni oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́ ti wá. +Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun rí nígbà kan. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọrun, kòríkòsùn Baba, ni ó fi ẹni tí Baba jẹ́ hàn. +Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?” +Òun ni ó wà pẹlu Ọlọrun ní ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé. +Ó sọ òtítọ́, kò parọ́, �� ní, “Èmi kì í ṣe Mesaya náà.” +Wọ́n wá bi í pé, “Ta wá ni ọ́? Ṣé Elija ni ọ́ ni?”Ó ní, “Èmi kì í ṣe Elija.”Wọ́n tún bi í pé, “Ìwọ ni wolii tí à ń retí bí?”Ó ní, “Èmi kọ́.” +Wọ́n bá tún bèèrè pé, “Ó dára, ta ni ọ́? Ó yẹ kí á lè rí èsì mú pada fún àwọn tí wọ́n rán wa wá. Kí ni o sọ nípa ara rẹ?” +Ó bá dáhùn gẹ́gẹ́ bí wolii Aisaya ti sọ pé:“Èmi ni ‘ohùn ẹni tí ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé:Ẹ ṣe ọ̀nà tí ó tọ́ fún Oluwa.’ ” +Àwọn Farisi ni ó rán àwọn eniyan sí i. +Wọ́n wá bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń ṣe ìrìbọmi nígbà tí kì í ṣe ìwọ ni Mesaya tabi Elija tabi wolii tí à ń retí?” +Johanu dá wọn lóhùn pé, “Omi ni èmi fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́, ẹnìkan wà láàrin yín tí ẹ kò mọ̀, +ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ṣugbọn n kò tó tú okùn bàtà rẹ̀.” +Ní Bẹtani tí ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani ni nǹkan wọnyi ti ṣẹlẹ̀, níbi tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi. +Ní ọjọ́ keji, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ. +Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, ninu gbogbo ohun tí a dá, kò sí ohun kan tí a dá lẹ́yìn rẹ̀. +Òun ni mo sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí ó jù mí lọ, nítorí ó ti wà kí á tó bí mi.’ +Èmi alára kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn kí á lè fi í han Israẹli ni mo ṣe wá, tí mò ń fi omi ṣe ìwẹ̀mọ́.” +Johanu tún jẹ́rìí pé, “Mo ti rí Ẹ̀mí tí ó sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà láti ọ̀run tí ó bà lé e, tí ó sì ń bá a gbé. +Èmi alára kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó rán mi láti máa ṣe ìrìbọmi ti sọ fún mi pé, ẹni tí mo bá rí tí Ẹ̀mí bá sọ̀kalẹ̀ lé lórí, tí ó bá ń bá a gbé, òun ni ẹni tí ó ń fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìwẹ̀mọ́. +Mo ti rí i, mo wá ń jẹ́rìí pé òun ni Ọmọ Ọlọrun.” +Ní ọjọ́ keji, bí Johanu ati àwọn meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti tún dúró, +ó tẹjú mọ́ Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun.” +Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn meji náà gbọ́, wọ́n tẹ̀lé Jesu. +Nígbà tí Jesu yipada, tí ó rí wọn tí wọn ń tẹ̀lé òun, ó bi wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń wá?”Wọ́n ní, “Rabi, níbo ni ò ń gbé?” (Ìtumọ̀ “Rabi” ni “Olùkọ́ni.”) +Ó ní, “Ẹ ká lọ, ẹ óo sì rí i.” Wọ́n bá bá a lọ, wọ́n rí ibi tí ó ń gbé. Wọ́n dúró lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí ó ti tó bí nǹkan agogo mẹrin ìrọ̀lẹ́. +Òun ni orísun ìyè, ìyè náà ni ìmọ́lẹ̀ aráyé. +Ọ̀kan ninu àwọn meji tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó tẹ̀lé Jesu ni Anderu arakunrin Simoni Peteru. +Lẹsẹkẹsẹ, Anderu rí Simoni arakunrin rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Àwa ti rí Mesaya!” (Ìtumọ̀ “Mesaya” ni “Kristi.”) +Ó bá mú un lọ sọ́dọ̀ Jesu.Jesu tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Johanu; Kefa ni a óo máa pè ọ́.” (Ìtumọ̀ “Kefa” ni “àpáta”, “Peteru” ni ní èdè Giriki.) +Ní ọjọ́ keji, bí Jesu ti fẹ́ máa lọ sí ilẹ̀ Galili, ó rí Filipi. Ó sọ fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” +Ará Bẹtisaida, ìlú Anderu ati ti Peteru, ni Filipi. +Filipi wá rí Nataniẹli, ó wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni tí Mose kọ nípa rẹ̀ ninu Ìwé Òfin, tí àwọn wolii tún kọ nípa rẹ̀, Jesu ọmọ Josẹfu ará Nasarẹti.” +Nataniẹli bi í pé, “Ṣé nǹkan rere kan lè ti Nasarẹti wá?”Filipi dá a lóhùn pé, “Wá wò ó.” +Jesu rí Nataniẹli bí ó ti ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ nípa rẹ̀ pé, “Wo ọmọlúwàbí, ọmọ Israẹli tí kò ní ẹ̀tàn ninu.” +Nataniẹli bi í pé, “Níbo ni o ti mọ̀ mí?”Jesu dá a lóhùn pé, “Kí Filipi tó pè ọ́, nígbà tí o wà ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, mo ti rí ọ.” +Nataniẹli wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ìwọ ni ọmọ Ọlọrun, ìwọ ni ọba Israẹli.” +Ìmọ́lẹ̀ náà ń tàn ninu òkùnkùn, òkùnkùn kò sì lè borí rẹ̀. +Jesu wí fún un pé, “Nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ ni o ṣe gbàgbọ́? Ìwọ yóo rí ohun tí ó jù yìí lọ.” +Ó tún wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹ óo rí ọ̀run tí yóo pínyà, ẹ óo wá rí àwọn angẹli Ọlọrun tí wọn óo máa gòkè, tí wọn óo tún máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ-Eniyan.” +Ọkunrin kan wà tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Johanu. +Òun ni ó wá gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, kí ó lè jẹ́rìí sí ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo eniyan lè torí ẹ̀rí rẹ̀ gbàgbọ́. +Kì í ṣe òun ni ìmọ́lẹ̀ náà, ṣugbọn ó wá láti jẹ́rìí ìmọ́lẹ̀ náà. +Èyí ni ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tí ó wá sinu ayé, tí ó ń tàn sí gbogbo aráyé. +Jesu Fi Aguntan Ṣe Àkàwé. +“Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ àgbàlá ilé tí àwọn aguntan ń sùn sí, ṣugbọn tí ó bá fo ìgànná wọlé, olè ati ọlọ́ṣà ni. +Olè kì í wá lásán, àfi kí ó wá jalè, kí ó wá pa eniyan, kí ó sì wá ba nǹkan jẹ́. Èmi wá kí eniyan lè ní ìyè, kí wọn lè ní i lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. +“Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-aguntan rere, mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan. +Alágbàṣe tí kì í ṣe olùṣọ́-aguntan, tí kì í sìí ṣe olówó aguntan, bí ó bá rí ìkookò tí ń bọ̀, a fi àwọn aguntan sílẹ̀, a sálọ. Ìkookò a gbé ninu àwọn aguntan lọ, a sì tú wọn ká, +nítorí alágbàṣe lásán ni, kò bìkítà fún àwọn aguntan. +Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Mo mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi náà sì mọ̀ mí, +gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi náà sì mọ Baba. Mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan. +Mo tún ní àwọn aguntan mìíràn tí kò sí ninu agbo yìí. Mo níláti dà wọ́n wá. Wọn yóo gbọ́ ohùn mi. Wọn yóo wá di agbo kan lábẹ́ olùṣọ́-aguntan kan. +“Ìdí rẹ̀ nìyí tí Baba fi fẹ́ràn mi nítorí mo ṣetán láti kú, kí n lè tún wà láàyè. +Ẹnikẹ́ni kò gba ẹ̀mí mi, ṣugbọn èmi fúnra mi ni mo yọ̀ǹda rẹ̀. Mo ní àṣẹ láti yọ̀ǹda rẹ̀, mo ní àṣẹ láti tún gbà á pada. Àṣẹ yìí ni mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ Baba mi.” +Ìyapa tún bẹ́ sáàrin àwọn Juu nítorí ọ̀rọ̀ yìí. +Ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà wọlé ni olùṣọ́-aguntan. +Ọpọlọpọ ninu wọn sọ pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ ti dàrú. Kí ni ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí?” +Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù lè la ojú afọ́jú?” +Ní àkókò òtútù-nini, ó tó àkókò Àjọ̀dún Ìyàsímímọ́ Tẹmpili tí wọn ń ṣe ní Jerusalẹmu, +Jesu ń rìn kiri ní apá ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Solomoni ninu Tẹmpili. +Àwọn Juu bá pagbo yí i ká, wọ́n sọ fún un pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóo tó fi ọkàn wa balẹ̀? Bí ìwọ bá ni Mesaya, sọ fún wa pàtó.” +Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo sọ fun yín, ẹ kò gbàgbọ́. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní orúkọ Baba mi ń jẹ́rìí mi, +ṣugbọn ẹ kò gbàgbọ́, nítorí ẹ kò sí ninu àwọn aguntan mi. +Àwọn aguntan mi a máa gbọ́ ohùn mi, mo mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tẹ̀lé mi. +Mo fún wọn ní ìyè ainipẹkun, wọn kò lè kú mọ́ laelae, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè já wọn gbà mọ́ mi lọ́wọ́. +Ohun tí Baba mi ti fún mi tóbi ju ohun gbogbo lọ. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè já a gbà mọ́ Baba mi lọ́wọ́. +Òun ni olùṣọ́nà ń ṣí ìlẹ̀kùn fún. Àwọn aguntan a máa gbọ́ ohùn rẹ̀, a sì máa pe àwọn aguntan rẹ̀ ní orúkọ, a máa kó wọn lọ jẹ. +Ọ̀kan ni èmi ati Baba mi.” +Àwọn Juu tún ṣa òkúta láti sọ lù ú. +Jesu wá bi wọ́n pé, “Ọpọlọpọ iṣẹ́ rere ni mo ti fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba. Nítorí èwo ni ẹ fi fẹ́ sọ mí ní òkúta ninu wọn?” +Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere ni a fi fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, nítorí ọ̀rọ̀ àfojúdi tí o sọ sí Ọlọrun ni; nítorí pé ìwọ tí ó jẹ́ eniyan sọ ara rẹ di Ọlọrun.” +Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣebí àkọsílẹ̀ kan wà ninu Òfin yín pé, ‘Ọlọrun sọ pé ọlọrun ni yín.’ +Ìwé Mímọ́ kò ṣe é parẹ́. Bí Ọlọrun bá pe àwọn tí ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ní ọlọ́run, +kí ló dé tí ẹ fi sọ pé mò ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọrun ni mí,’ èmi tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó rán wá sí ayé? +Bí n kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́. +Ṣugbọn bí mo bá ń ṣe é, èmi kọ́ ni kí ẹ gbàgbọ́, àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ni kí ẹ gbàgbọ́. Èyí yóo jẹ́ kí ẹ wòye, kí ẹ wá mọ̀ pé Baba wà ninu mi, ati pé èmi náà wà ninu Baba.” +Nígbà náà ni wọ́n tún ń wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn ó jáde kúrò ní àrọ́wọ́tó wọn. +Nígbà tí gbogbo àwọn aguntan rẹ̀ bá jáde, a máa lọ níwájú wọn, àwọn aguntan a sì tẹ̀lé e nítorí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. +Ó tún pada lọ sí òdìkejì odò Jọdani níbi tí Johanu tí ń ṣe ìrìbọmi ní àkọ́kọ́, ó bá ń gbé ibẹ̀. +Ọpọlọpọ eniyan lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń sọ pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan, ṣugbọn gbogbo ohun tí ó sọ nípa ọkunrin yìí ni ó rí bẹ́ẹ̀.” +Ọpọlọpọ eniyan bá gbà á gbọ́ níbẹ̀. +Aguntan kò jẹ́ tẹ̀lé àlejò, sísá ni wọ́n máa ń sá fún un, nítorí wọn kò mọ ohùn àlejò.” +Òwe yìí ni Jesu fi bá wọn sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ó ń bá wọn sọ kò yé wọn. +Jesu tún sọ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn aguntan. +Olè ati ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí wọ́n ti wá ṣiwaju mi. Ṣugbọn àwọn aguntan kò gbọ́ ti wọn. +Èmi ni ìlẹ̀kùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé yóo rí ìgbàlà, yóo máa wọlé, yóo máa jáde, yóo sì máa rí oúnjẹ jẹ. +Ikú Lasaru. +Ọkunrin kan tí ń jẹ́ Lasaru ń ṣàìsàn. Ní Bẹtani ni ó ń gbé, ní ìlú kan náà pẹlu Maria ati Mata arabinrin rẹ̀. +Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá ń rìn lálẹ́ níí kọsẹ̀, nítorí kò sí ìmọ́lẹ̀ ninu rẹ̀.” +Lẹ́yìn tí ó ti sọ báyìí tán, ó sọ fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa ti sùn, mò ń lọ jí i.” +Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Oluwa, bí ó bá sùn, yóo tún jí.” +Ohun tí Jesu ń sọ̀rọ̀ bá ni ikú Lasaru, ṣugbọn wọ́n rò pé nípa oorun sísùn ni ó ń sọ. +Nígbà náà ni Jesu wá wí fún wọn pàtó pé, “Lasaru ti kú. +Ó dùn mọ́ mi nítorí yín pé n kò sí níbẹ̀, kí ẹ lè gbàgbọ́. Ẹ jẹ́ kí á lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” +Nígbà náà ni Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Ìbejì”) sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ kí àwa náà lè bá a kú.” +Nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé ó ti tó ọjọ́ mẹrin tí òkú náà ti wà ninu ibojì. +Bẹtani kò jìnnà sí Jerusalẹmu, kò ju ibùsọ̀ meji lọ. +Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu ni wọ́n wá láti Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Mata ati Maria láti tù wọ́n ninu nítorí ikú arakunrin wọn. +Maria yìí ni obinrin tí ó tú òróró olóòórùn dídùn sára Oluwa ní ọjọ́ kan, tí ó fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jesu. Lasaru tí ó ń ṣàìsàn jẹ́ arakunrin Maria yìí. +Nígbà tí Mata gbọ́ pé Jesu ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀. Ṣugbọn Maria jókòó ninu ilé. +Mata sọ fún Jesu pé, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú! +Ṣugbọn nisinsinyii náà, mo mọ̀ pé ohunkohun tí o bá bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, yóo ṣe é fún ọ.” +Jesu wí fún un pé, “Arakunrin rẹ yóo jí dìde.” +Mata dá a lóhùn pé, “Mo mọ̀ pé yóo jí dìde ní ajinde ọjọ́ ìkẹyìn.” +Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ajinde ati ìyè. Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, sibẹ yóo yè. +Gbogbo ẹni tí ó bá wà láàyè, tí ó bá gbà mí gbọ́, kò ní kú laelae. Ǹjẹ́ o gba èyí gbọ́?” +Ó dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, mo gbàgbọ́ pé ìwọ ni Mesaya Ọmọ Ọlọrun tí ó ń bọ̀ wá sí ayé.” +Nígbà tí Mata ti sọ báyìí tán, ó lọ pe Maria arabinrin rẹ̀ sí ìkọ̀kọ̀. Ó ní, “Olùkọ́ni ti dé, ó ń pè ọ́.” +Bí Maria ti gbọ́, ó dìde kíá, ó bá lọ sọ́dọ̀ Jesu. +Àwọn arabinrin mejeeji yìí ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Jesu pé, “Oluwa, ẹni tí o fẹ́ràn ń ṣàìsàn.” +(Jesu kò tíì wọ ìlú, ó wà ní ibi tí Mata ti pàdé rẹ̀.) +Nígbà tí àwọn Juu tí ó wà ninu ilé pẹlu Maria, tí wọn ń tù ú ninu, rí i pé ó sáré dìde, ó jáde, àwọn náà tẹ̀lé e, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti lọ sunkún ni. +Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.” +Nígbà tí Jesu rí i tí ó ń sunkún, tí àwọn Juu tí ó bá a jáde tún ń sunkún, orí rẹ̀ wú, ọkàn rẹ̀ wá bàjẹ́. +Ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?”Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wá wò ó.” +Ni Jesu bá bú sẹ́kún. +Nígbà náà ni àwọn Juu sọ pé, “Ẹ ò rí i bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!” +Àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Ọkunrin yìí tí ó la ojú afọ́jú, ǹjẹ́ kò lè ṣe é kí ọkunrin yìí má fi kú?” +Orí Jesu tún wú, ó bá lọ síbi ibojì. Ninu ihò òkúta ni ibojì náà wà, òkúta sì wà ní ẹnu ọ̀nà rẹ̀. +Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.”Mata, arabinrin ẹni tí ó kú, sọ fún un pé, “Oluwa, ó ti ń rùn, nítorí ó ti di òkú ọjọ́ mẹrin!” +Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àìsàn yìí kì í ṣe ti ikú, fún ògo Ọlọrun ni, kí á lè ṣe Ọmọ Ọlọrun lógo nípa rẹ̀ ni.” +Jesu wí fún un pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé bí o bá gbàgbọ́ ìwọ yóo rí ògo Ọlọrun.” +Wọ́n bá gbé òkúta náà kúrò. Jesu gbé ojú sókè, ó ní, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí ò ń gbọ́ tèmi. +Mo mọ̀ pé nígbà gbogbo ni ò ń gbọ́ tèmi, ṣugbọn nítorí ti àwọn eniyan tí ó dúró yíká ni mo ṣe sọ èyí kí wọ́n lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni o rán mi níṣẹ́.” +Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó kígbe sókè pé, “Lasaru, jáde wá!” +Ẹni tí ó ti kú náà bá jáde pẹlu aṣọ òkú tí wọ́n fi wé e lọ́wọ́ ati lẹ́sẹ̀ ati ọ̀já tí wọ́n fi dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, kí ẹ jẹ́ kí ó máa lọ.” +Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu tí ó wá sọ́dọ̀ Maria gba Jesu gbọ́ nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣe. +Ṣugbọn àwọn kan ninu wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisi, wọ́n lọ sọ ohun gbogbo tí Jesu ṣe. +Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi bá pe ìgbìmọ̀, wọ́n ní, “Kí ni a óo ṣe o, nítorí ọkunrin yìí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu pupọ? +Bí a bá fi í sílẹ̀ báyìí, gbogbo eniyan ni yóo gbà á gbọ́, àwọn ará Romu yóo bá wá, wọn yóo wo Tẹmpili yìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo pa orílẹ̀-èdè wa run.” +Nígbà náà ni ọ̀kan ninu wọn, Kayafa, tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ní ọdún náà, sọ fún wọn pé, “Ẹ kò mọ nǹkankan! +Jesu fẹ́ràn Mata ati arabinrin rẹ̀ ati Lasaru. +Ẹ kò rí i pé ó sàn kí ẹnìkan kú fún àwọn eniyan jù pé kí gbogbo orílẹ̀-èdè ṣègbé!” +Kì í ṣe àròsọ ti ara rẹ̀ ni ó fi sọ gbolohun yìí, ṣugbọn nítorí ó jẹ́ olórí alufaa ní ọdún náà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ni, pé Jesu yóo kú fún orílẹ̀-èdè wọn. +Kì í wá ṣe fún orílẹ̀-èdè wọn nìkan, ṣugbọn kí àwọn ọmọ Ọlọrun tí ó fọ́nká lè papọ̀ di ọ̀kan. +Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ń gbèrò ọ̀nà tí wọn yóo fi pa Jesu. +Nítorí náà, Jesu kò rìn ní gbangba mọ́ láàrin àwọn Juu, ṣugbọn ó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú kan lẹ́bàá aṣálẹ̀, tí ó ń jẹ́ Efuraimu. Níbẹ̀ ni ó ń gbé pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. +Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ti àwọn Juu, ọ̀pọ̀ eniyan gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti ìgbèríko, kí ó tó tó àkókò àjọ̀dún, kí wọ́n lè ṣe ìwẹ̀mọ́ fún àjọ̀dún náà. +Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá Jesu, wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti dúró ninu Tẹmpili pé, “Kí ni ẹ rò? Ǹjẹ́ ó jẹ́ wá sí àjọ̀dún yìí?” +Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi ti pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ ibi tí Jesu wà, kí ó wá sọ, kí wọ́n lè mú un. +Nígbà tí Jesu gbọ́ pé Lasaru ń ṣàìsàn, kò kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ́ meji. +Lẹ́yìn náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á tún pada lọ sí Judia.” +Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, láìpẹ́ yìí ni àwọn Juu ń fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, o tún fẹ́ lọ sibẹ?” +Jesu ní, “Ṣebí wakati mejila ni ó wà ninu ọjọ́ kan? Bí ẹnikẹ́ni bá rìn ní ọ̀sán kò ní kọsẹ̀, nítorí ó ń fi ìmọ́lẹ̀ ayé yìí ríran. +Maria Tú Òróró Dà Sára Jesu ní Bẹtani. +Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹfa, Jesu lọ sí Bẹtani níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó kú, tí Jesu jí dìde. +Àwọn olórí alufaa bá pinnu láti pa Lasaru, +nítorí pé nítorí rẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn Juu ṣe ń kúrò ninu ẹ̀sìn wọn, tí wọn ń gba Jesu gbọ́. +Ní ọjọ́ keji, ọpọlọpọ eniyan tí ó wá ṣe àjọ̀dún gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. +Wọ́n bá mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n ń kígbe pé, “Hosana! Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Oluwa ati ọba Israẹli.” +Jesu rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó bá gùn un, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, +“Má bẹ̀rù mọ́, ọdọmọbinrin Sioni,Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá,ó gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” +Gbogbo nǹkan wọnyi kò yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní àkókò yìí, ṣugbọn nígbà tí a ti ṣe Jesu lógo, wọ́n ranti pé a ti kọ gbogbo nǹkan wọnyi nípa rẹ̀ ati pé wọ́n ti ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí i. +Àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu Jesu nígbà tí ó fi pe Lasaru jáde kúrò ninu ibojì, tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú, ń ròyìn ohun tí wọ́n rí. +Nítorí èyí ni àwọn eniyan ṣe lọ pàdé rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ó ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí. +Àwọn Farisi bá ń bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jókòó lásán ni! Òfo ni gbogbo làálàá yín já sí! Ẹ kò rí i pé gbogbo eniyan ni wọ́n ti tẹ̀lé e tán!” +Wọ́n se àsè kan fún un níbẹ̀. Mata ń ṣe ètò gbígbé oúnjẹ kalẹ̀; Lasaru wà ninu àwọn tí ó ń bá Jesu jẹun. +Àwọn Giriki mélòó kan wà ninu àwọn tí ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn ní àkókò àjọ̀dún náà. +Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Filipi tí ó jẹ́ ará Bẹtisaida, ìlú kan ní Galili, wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà, a fẹ́ rí Jesu.” +Filipi lọ sọ fún Anderu, Anderu ati Filipi bá jọ lọ sọ fún Jesu. +Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò náà dé wàyí tí a óo ṣe Ọmọ-Eniyan lógo. +Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹyọ irúgbìn kan kò bá bọ́ sílẹ̀, kí ó kú, òun nìkan ni yóo dá wà. Ṣugbọn bí ó bá kú, á mú ọpọlọpọ èso wá. +Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹ̀mí rẹ̀ yóo pàdánù rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ ní ayé yìí yóo pa á mọ́ títí di ìyè ainipẹkun. +Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ iranṣẹ mi, ó níláti tẹ̀lé mi. Níbi tí èmi alára bá wà, níbẹ̀ ni iranṣẹ mi yóo wà. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ iranṣẹ mi, Baba mi yóo dá a lọ́lá.” +Jesu bá tún sọ pé, “Ọkàn mí dàrú nisinsinyii. Kí ni ǹ bá wí? Ọkàn kan ń sọ pé kí n wí pé, ‘Baba, yọ mí kúrò ninu àkókò yìí.’ Ṣugbọn nítorí àkókò yìí gan-an ni mo ṣe wá sí ayé. +Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.”Ohùn kan bá wá láti ọ̀run, ó ní, “Mo ti ṣe é lógo ná, èmi óo sì tún ṣe é lógo sí i.” +Ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan tí wọ́n dúró, tí wọ́n gbọ́, ń sọ pé, “Ààrá sán!” Àwọn ẹlòmíràn ń sọ pé, “Angẹli ló bá a sọ̀rọ̀.” +Nígbà náà ni Maria dé, ó mú ìgò kékeré kan lọ́wọ́. Ojúlówó òróró ìpara kan, olówó iyebíye ni ó wà ninu ìgò náà. Ó bá tú òróró yìí sí Jesu lẹ́sẹ̀, ó ń fi irun orí rẹ̀ nù ún. Òórùn òróró náà bá gba gbogbo ilé. +Jesu wí fún wọn pé, “Ohùn yìí kò wá nítorí tèmi bí kò ṣe nítorí tiyín. +Àkókò tó fún ìdájọ́ ayé yìí. Nisinsinyii ni a óo lé aláṣẹ ayé yìí jáde. +Ní tèmi, bí a bá gbé mi sókè kúrò láyé, n óo fa gbogbo eniyan sọ́dọ̀ mi.” +Ó sọ èyí, ó fi ṣe àkàwé irú ikú tí yóo kú. +Àwọn eniyan bi í pé, “A gbọ́ ninu òfin pé Mesaya wà títí lae. Kí ni ìtumọ̀ ohun tí o sọ pé dandan ni kí á gbé Ọmọ-Eniyan sókè? Ta ni ń jẹ́ Ọmọ-Eniyan?” +Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìmọ́lẹ̀ wà láàrin yín fún àkókò díẹ̀ sí i. Ẹ máa rìn níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má baà bò yín mọ́lẹ̀. Ẹni tí ó bá ń rìn ninu òkùnkùn kò mọ ibi tí ó ń lọ. +Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ náà gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀.”Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó fara pamọ́ fún wọn. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lójú wọn, sibẹ wọn kò gbà á gbọ́. +Èyí mú kí ọ̀rọ̀ wolii Aisaya ṣẹ nígbà tí ó sọ pé,“Oluwa, ta ni ó gba ìròyìn wa gbọ́?Ta ni a fi agbára Oluwa hàn fún?” +Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Aisaya tún sọ pé, +Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, sọ pé, +“Ojú wọn ti fọ́,ọkàn wọn sì ti le;kí wọn má baà fi ojú wọn ríran,kí òye má baà yé wọn.Kí wọn má baà yipada,kí n má baà wò wọ́n sàn.” +Aisaya sọ nǹkan wọnyi nítorí ó rí ògo Jesu, ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀. +Sibẹ ọpọlọpọ ninu àwọn aṣaaju gbà á gbọ́; ṣugbọn wọn kò jẹ́wọ́ nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Farisi, kí wọn má baà yọ wọ́n kúrò ninu àwùjọ; +nítorí wọ́n fẹ́ràn ìyìn eniyan ju ìyìn Ọlọrun lọ. +Jesu bá kígbe pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, kì í ṣe èmi ni ó gbàgbọ́ bíkòṣe ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. +Ẹni tí ó bá rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi. +Mo wá sinu ayé bí ìmọ́lẹ̀, kí ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ má baà wà ninu òkùnkùn. +Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò bá pa á mọ́, èmi kò ní dá a lẹ́jọ́, nítorí n kò wá sí ayé láti ṣe ìdájọ́, ṣugbọn mo wá láti gba aráyé là. +Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, ó ní ohun tí yóo dá a lẹ́jọ́, ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ ni yóo dá a lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn. +Nítorí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ti ara mi ni mò ń sọ, bíkòṣe ti Baba tí ó rán mi níṣẹ́, tí ó ti fún mi ní àṣẹ ohun tí n óo sọ ati ohun tí n óo wí. +“Kí ló dé tí a kò ta òróró yìí ní nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, kí á pín in fún àwọn talaka?” +Mo mọ̀ pé òfin rẹ̀ ń tọ́ni sí ìyè ainipẹkun. Nítorí náà, bí Baba ti sọ fún mi pé kí n wí, bẹ́ẹ̀ gan-an ni mò ń sọ.” +Kì í ṣe nítorí pé ó bìkítà fún àwọn talaka ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀; nítorí pé ó jẹ́ olè ni. Òun ni akápò; a máa jí ninu owó tí wọn bá fi pamọ́. +Jesu dá a lóhùn pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí ó fi pamọ́ di ọjọ́ ìsìnkú mi. +Nígbà gbogbo ni àwọn talaka wà lọ́dọ̀ yín, ṣugbọn èmi kò ní sí lọ́dọ̀ yín nígbà gbogbo.” +Nígbà tí ọpọlọpọ ninu àw��n Juu mọ̀ pé Jesu wà ní Bẹtani, wọ́n lọ sibẹ, kì í ṣe nítorí ti Jesu nìkan, ṣugbọn nítorí kí wọ́n lè rí Lasaru tí Jesu jí dìde kúrò ninu òkú. +Jesu Wẹ Ẹsẹ̀ Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀. +Nígbà tí àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ kan, Jesu mọ̀ pé àkókò tó, tí òun yóo kúrò láyé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba. Fífẹ́ tí ó fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀ tó wà láyé yìí, ó fẹ́ràn wọn dé òpin. +Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí ó bá ti wẹ̀ nílé, tí ó bá jáde, kò sí ohun tí ó kù jù pé kí á fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, gbogbo ara rẹ̀ á wá di mímọ́. Ẹ̀yin mọ́, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo yín.” +Ó ti mọ ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́; nítorí náà ni ó ṣe sọ pé, “Kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́.” +Nígbà tí ó ti fọ ẹsẹ̀ wọn tán, ó wọ agbádá rẹ̀, ó bá tún jókòó. Ó wá bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe si yín? +Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. +Bí èmi Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ máa fọ ẹsẹ̀ ẹnìkejì yín. +Àpẹẹrẹ ni mo fi fun yín pé, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe. +Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé: ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ, iranṣẹ kò ju ẹni tí ó rán an níṣẹ́ lọ. +Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n. +“Gbogbo yín kọ́ ni ọ̀rọ̀ mi yìí kàn. Mo mọ àwọn tí mo yàn. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ níláti ṣẹ tí ó sọ pé, ‘Ẹni tí ó ń bá mi jẹun ni ó ń jìn mí lẹ́sẹ̀.’ +Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè mọ ẹni tí èmi í ṣe nígbà tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ tán. +Bí wọ́n ti ń jẹun, Èṣù ti fi sí Judasi ọmọ Simoni Iskariotu lọ́kàn láti fi Jesu lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. +Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.” +Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó bá wí tẹ̀dùntẹ̀dùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.” +Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú; nítorí ohun tí Jesu sọ rú wọn lójú. +Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí. +Simoni Peteru bá ṣẹ́jú sí i pé kí ó bèèrè pé ta ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí. +Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà túbọ̀ súnmọ́ Jesu sí i, ó bi í pé, “Oluwa, ta ni rí?” +Jesu dáhùn pé, “Ẹni tí mo bá fún ní òkèlè lẹ́yìn tí mo bá ti fi run ọbẹ̀ tán ni ẹni náà.” Nígbà tí ó ti fi òkèlè run ọbẹ̀, ó mú un fún Judasi ọmọ Iskariotu. +Lẹ́yìn tí Judasi ti gba òkèlè náà, Satani wọ inú rẹ̀. Jesu bá wí fún un pé, “Tètè ṣe ohun tí o níí ṣe.” +Kò sí ẹnìkan ninu àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun tí ó mọ ìdí tí Jesu fi sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un. +Nígbà tí ó jẹ́ pé Judasi ni akápò, àwọn mìíràn ń rò pé ohun tí Jesu sọ fún un ni pé, “Lọ ra àwọn ohun tí a óo lò fún Àjọ̀dún Ìrékọjá, tabi ohun tí a óo fún àwọn talaka.” +Jesu mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, ati pé ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun sì ń lọ. +Lẹsẹkẹsẹ tí Judasi ti gba òkèlè náà tán, ó jáde lọ. Ilẹ̀ ti ṣú nígbà náà. +Nígbà tí Judasi jáde, Jesu wí pé, “Nisinsinyii ni ògo Ọmọ-Eniyan wá yọ. Ògo Ọlọrun pàápàá yọ lára Ọmọ-Eniyan. +Bí ògo Ọlọrun bá wá yọ lára rẹ̀, Ọlọrun fúnrarẹ̀ yóo mú kí ògo Ọmọ-Eniyan yọ; lọ́gán ni yóo mú kí ògo rẹ̀ yọ. +Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii. +Òfin titun ni mo fi fun yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín ni kí ẹ fẹ́ràn ara yín. +Èyí ni yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.” +Simoni Peteru bi í pé, “Oluwa, níbo ni ò ń lọ?”Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí mò ń lọ, ìwọ kò lè tẹ̀lé mi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ìwọ óo tẹ̀lé mi.” +Peteru bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí n kò lè tẹ̀lé ọ nisinsinyii? Mo ṣetán láti kú nítorí rẹ.” +Jesu dá a lóhùn pé, “O ṣetán láti kú nítorí mi? Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, kí àkùkọ tó kọ ìwọ óo sẹ́ mi lẹẹmẹta. +Ó bá dìde nídìí oúnjẹ, ó bọ́ agbádá rẹ̀ sílẹ̀, ó mú aṣọ ìnura, ó lọ́ ọ mọ́ ìbàdí, +ó bu omi sinu àwokòtò kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń fi aṣọ ìnura tí ó lọ́ mọ́ ìbàdí nù wọ́n lẹ́sẹ̀. +Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Simoni Peteru, Peteru bi í pé, “Oluwa, ìwọ ni o fẹ́ fọ ẹsẹ̀ mi?” +Jesu dá a lóhùn pé, “O kò mọ ohun tí mò ń ṣe nisinsinyii; ṣugbọn yóo yé ọ tí ó bá yá.” +Peteru dá a lóhùn pé, “O kò ní fọ ẹsẹ̀ mi laelae!”Jesu wí fún un pé, “Bí n kò bá wẹ̀ ọ́, a jẹ́ pé ìwọ kò ní nǹkankan ṣe pẹlu mi.” +Simoni Peteru bá sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Oluwa, ẹsẹ̀ mi nìkan kọ́, ati ọwọ́ ati orí mi ni kí o fọ̀ pẹlu.” +Jesu Ni Ọ̀nà Dé Ọ̀dọ̀ Baba. +“Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú. Ẹ gba Ọlọrun gbọ́, kí ẹ sì gba èmi náà gbọ́. +Àbí o kò gbàgbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi ni? Èmi fúnra mi kọ́ ni mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fun yín. Baba tí ó ń gbé inú mi ni ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. +Ẹ gbà mí gbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí iṣẹ́ wọnyi. +Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ yóo ṣe àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe; yóo tilẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó ju ìwọ̀nyí lọ, nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba. +Èmi yóo ṣe ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi, kí ògo Baba lè yọ lára Ọmọ. +Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́wọ́ mi ní orúkọ mi, èmi yóo ṣe é. +“Bí ẹ bá fẹ́ràn mi, ẹ óo pa òfin mi mọ́. +N óo bèèrè lọ́wọ́ Baba, yóo wá fun yín ní Alátìlẹ́yìn mìíràn tí yóo wà pẹlu yín títí lae. +Òun ni Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn. Ayé kò lè gbà á nítorí ayé kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. Ṣugbọn ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, nítorí ó ń ba yín gbé, ó sì wà ninu yín. +“Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ bí aláìlárá. Mò ń pada bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. +Láìpẹ́, ayé kò ní rí mi mọ́, ṣugbọn ẹ̀yin yóo rí mi. Nítorí èmi wà láàyè, ẹ̀yin náà yóo wà láàyè. +Yàrá pupọ ni ó wà ninu ilé Baba mi. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ n óo sọ fun yín pé mò ń lọ pèsè àyè sílẹ̀ dè yín? +Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin yóo mọ̀ pé èmi wà ninu Baba mi, ati pé ẹ̀yin wà ninu mi, èmi náà sì wà ninu yín. +“Ẹni tí ó bá gba òfin mi, tí ó sì pa wọ́n mọ́, òun ni ó fẹ́ràn mi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn mi, Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi náà yóo fẹ́ràn rẹ̀, n óo sì fi ara mi hàn án.” +Judasi keji, (kì í ṣe Judasi Iskariotu), bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí o ṣe wí pé o kò ní fi ara rẹ han aráyé, ṣugbọn àwa ni ìwọ óo fi ara hàn?” +Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn mi yóo tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi ati Baba mi yóo wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a óo fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùgbé. +Ẹni tí kò bá fẹ́ràn mi kò ní tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Ọ̀rọ̀ tí ẹ ń gbọ́ kì í ṣe tèmi, ti Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni. +“Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ yín. +Ṣugbọn Alátìlẹ́yìn náà, Ẹ̀mí Mímọ́ tí Baba yóo rán wá ní orúkọ mi, ni yóo kọ yín, tí yóo sì ran yín létí ohun gbogbo tí mo sọ fun yín. +“Alaafia ni mo fi sílẹ̀ fun yín. Alaafia mi ni mo fun yín. Kì í ṣe bí ayé ti í fúnni ni mo fun yín. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín. +Ẹ gbọ́ nígbà tí mo sọ fun yín pé, ‘Mò ń lọ, ṣugbọn n óo tún pada wá sọ́dọ̀ yín.’ Bí ẹ bá fẹ́ràn mi ni, yíyọ̀ ni ẹ̀ bá máa yọ̀ pé, mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí Baba jù mí lọ. +Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè gbàgbọ́ nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ tán. +Bí mo bá lọ pèsè àyè sílẹ̀ dè yín, n óo tún pada wá láti mu yín lọ sọ́dọ̀ ara mi, kí ẹ lè wà níbi tí èmi pàápàá bá wà. +N kò tún ní ohun pupọ ba yín sọ mọ́, nítorí aláṣẹ ayé yìí ń bọ̀. Kò ní agbára kan lórí mi. +Ṣugbọn kí ayé lè mọ̀ pé mo fẹ́ràn Baba ni mo ṣe ń ṣe bí Baba ti pàṣẹ fún mi.“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á kúrò níhìn-ín. +Ẹ kúkú ti mọ ọ̀nà ibi tí mò ń lọ.” +Tomasi wí fún un pé, “Oluwa, a kò mọ ibi tí ò ń lọ, báwo ni a ti ṣe lè mọ ọ̀nà ibẹ̀?” +Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi. +Bí ẹ bá ti mọ̀ mí, ẹ óo mọ Baba mi. Láti àkókò yìí, ẹ ti mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.” +Filipi sọ fún un pé, “Oluwa, fi Baba hàn wá, èyí náà sì tó wa.” +Jesu wí fún un pé, “Bí mo ti pẹ́ lọ́dọ̀ yín tó yìí, sibẹ ìwọ kò mọ̀ mí, Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi ti rí Baba. Kí ló dé tí o fi tún ń sọ pé, ‘Fi Baba hàn wá?’ +Jesu Ni Igi Àjàrà. +“Èmi ni àjàrà tòótọ́. Baba mi ni àgbẹ̀ tí ń mójútó ọgbà àjàrà. +Bí ẹ bá pa òfin mi mọ́, ẹ óo máa gbé inú ìfẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì ń gbé inú ìfẹ́ rẹ̀. +“Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ayọ̀ mi lè wà ninu yín, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. +Àṣẹ mi nìyí; ẹ fẹ́ràn ara yín gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín. +Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó ju èyí lọ, pé ẹnìkan kú nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. +Ọ̀rẹ́ mi ni yín bí ẹ bá ń ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. +N kò pè yín ní ọmọ-ọ̀dọ̀ mọ́, nítorí ọmọ-ọ̀dọ̀ kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Ṣugbọn mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Baba mi ni mo ti fihàn yín. +Kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ yàn mí. Èmi ni mo yàn yín, tí mo ran yín pé kí ẹ lọ máa so èso tí kò ní bàjẹ́, kí Baba lè fun yín ní ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi. +Àṣẹ yìí ni mo pa fun yín: ẹ fẹ́ràn ara yín. +“Bí aráyé bá kórìíra yín, kí ẹ mọ̀ pé èmi ni wọ́n kọ́ kórìíra ṣáájú yín. +Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé ni yín, ayé ìbá fẹ́ràn yín bí àwọn ẹni tirẹ̀. Ṣugbọn ẹ kì í ṣe ti ayé nítorí mo ti yàn yín kúrò ninu ayé; ìdí rẹ̀ nìyí tí ayé fi kórìíra yín. +Gígé ni yóo gé gbogbo ẹ̀ka ara mi tí kò bá so èso, ṣugbọn yóo re ọwọ́ gbogbo ẹ̀ka tí ó bá ń so èso, kí wọ́n lè mọ́, kí wọ́n sì lè máa so sí i lọpọlọpọ. +Ẹ ranti ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín, pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ kò ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ṣe inúnibíni mi, wọn yóo ṣe inúnibíni yín. Bí wọ́n bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yóo pa ti ẹ̀yin náà mọ́. +Wọn yóo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi si yín nítorí tèmi, nítorí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. +Bí n kò bá wá láti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọn kò ní àwáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. +Ẹni tí ó bá kórìíra mi, kórìíra Baba mi. +Bí n kò bá ṣe irú iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ mi, sibẹ wọ́n kórìíra èmi ati Baba mi. +Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ ninu Òfin wọn lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’ +“Nígbà tí Alátìlẹ́yìn tí n óo rán si yín láti ọ̀dọ̀ Baba bá dé, àní Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, yóo jẹ́rìí nípa mi. +Ẹ̀yin náà yóo sì jẹ́rìí mi nítorí ẹ ti wà pẹlu mi láti ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mi. +Ẹ̀yin ti di mímọ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín. +Ẹ máa gbé inú mi, èmi óo máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ àfi bí ó bá wà lára igi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò lè so èso àfi bí ẹ bá ń gbé inú mi. +“Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó bá ń gbé inú mi, tí èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀, yóo máa so èso pupọ. Ẹ kò lè dá ohunkohun ṣe lẹ́yìn mi. +Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbé inú mi, a óo jù ú sóde bí ẹ̀ka, yóo sì gbẹ; wọn óo mú un, wọn óo sì fi dáná, yóo bá jóná. +Bí ẹ bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi ń gbé inú yín, ẹ óo bèèrè ohunkohun tí ẹ bá fẹ́, ẹ óo sì rí i gbà. +Báyìí ni ògo Baba mi yóo ṣe yọ, pé kí ẹ máa so ọpọlọpọ èso. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi. +Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ràn mi, bẹ́ẹ̀ ni mo fẹ́ràn yín. Ẹ máa gbé inú ìfẹ́ mi. +Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́. +“Mo sọ gbogbo nǹkan yìí fun yín kí igbagbọ yín má baà yẹ̀. +Wọ́n ṣìnà ní ti òdodo nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ kò sì ní rí mi mọ́. +Wọ́n ṣìnà ní ti ìdájọ́ nítorí pé Ọlọrun ti dá aláṣẹ ayé yìí lẹ́bi. +“Ọ̀rọ̀ tí mo tún fẹ́ ba yín sọ pọ̀, ṣugbọn ọkàn yin kò lè gbà á ní àkókò yìí. +Ṣugbọn nígbà tí Ẹ̀mí òtítọ́ tí mo wí bá dé, yóo tọ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo. Nítorí kò ní sọ ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀; gbogbo ohun tí ó bá gbọ́ ni yóo sọ. Yóo sọ àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fun yín. +Yóo fi ògo mi hàn nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni yóo ti gba àwọn ohun tí yóo sọ fun yín. +Tèmi ni ohun gbogbo tí Baba ní. Ìdí nìyí ti mo ṣe sọ pé ohun tí ó bá gbà láti ọ̀dọ̀ mi ni yóo sọ fun yín. +“Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi.” +Àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ ohun tí ó wí fún wa yìí, ‘Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi?’ Kí tún ni ìtumọ̀, ‘Nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba?’ ” +Wọ́n tún ń sọ pé, “Kí ni ìtumọ̀ ‘Láìpẹ́’ tí ó ń wí yìí? Ohun tí ó ń sọ kò yé wa.” +Jesu mọ̀ pé wọ́n ń fẹ́ bi òun léèrè ọ̀rọ̀ yìí. Ó wá wí fún wọn pé, “Nítorí èyí ni ẹ ṣe ń bá ara yín jiyàn, nítorí mo sọ pé, ‘Laìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́,’ ati pé, ‘Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo tún rí mi?’ +Wọn yóo le yín jáde kúrò ninu ilé ìpàdé wọn. Èyí nìkan kọ́, àkókò ń bọ̀ tí ó jẹ́ pé ẹni tí ó bá ṣe ikú pa yín yóo rò pé òun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn sí Ọlọrun ni. +Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ óo sunkún, ẹ óo ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn inú aráyé yóo dùn. Ẹ óo dààmú ṣugbọn ìdààmú yín yóo di ayọ̀. +Nígbà tí aboyún bá ń rọbí, ó gbọdọ̀ jẹ ìrora, nítorí àkókò ìkúnlẹ̀ rẹ̀ tó. Ṣugbọn nígbà tí ó bà bímọ tán, kò ní ranti gbogbo ìrora rẹ̀ mọ́, nítorí ayọ̀ pé ó bí ọmọ kan sinu ayé. +Bákan náà ni: inú yín bàjẹ́ nisinsinyii, ṣugbọn n óo tún ri yín, inú yín yóo wá dùn, ẹnikẹ́ni kò ní lè mú ayọ̀ yín kúrò lọ́kàn yín. +“Ní ọjọ́ náà, ẹ kò ní bi mí léèrè ohunkohun. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́dọ̀ Baba ní orúkọ mi, yóo fun yín. +Ẹ kò ì tíì bèèrè ohunkohun ní orúkọ mi títí di ìsinsìnyìí. Ẹ bèèrè, ẹ óo sì rí gbà, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. +“Bí òwe bí òwe ni mo ti ń sọ àwọn nǹkan yìí fun yín. Ṣugbọn àkókò ń bọ̀ nígbà tí n kò ní fi òwe ba yín sọ̀rọ̀ mọ́, kedere ni n óo máa sọ̀rọ̀ nípa Baba fun yín nígbà náà. +Ní ọjọ́ náà, ẹ óo bèèrè nǹkan ní orúkọ mi, n kò ní wí fun yín pé èmi yóo ba yín bẹ Baba. +Nítorí Baba fúnrarẹ̀ fẹ́ràn yín nítorí pé ẹ̀yin náà fẹ́ràn mi, ẹ ti gbàgbọ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. +Mo wá láti ọ̀dọ̀ Baba, mo jáde wá sinu ayé, n óo tún fi ayé sílẹ̀ láti lọ sọ́dọ̀ Baba.” +Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé, “Kedere ni ò ń sọ̀rọ̀ nisinsinyii, o kò sọ̀rọ̀ lówe lówe mọ́. +Wọn yóo ṣe nǹkan wọnyi nítorí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí. +A wá mọ̀ wàyí pé o mọ ohun gbogbo, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìgbà tí eniyan bá bi ọ́ kí o tó dáhùn ọ̀rọ̀. Nítorí náà, a gbàgbọ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni o ti wá.” +Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wá gbàgbọ́ nisinsinyii? +Àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ ti dé, nígbà tí ẹ óo túká, tí olukuluku yín yóo lọ sí ilé rẹ̀, tí ẹ óo fi èmi nìkan sílẹ̀. Ṣugbọn kò ní jẹ́ èmi nìkan nítorí Baba wà pẹlu mi. +Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ẹ lè ní alaafia nípa wíwà ninu mi. Ẹ óo ní ìpọ́njú ninu ayé, ṣugbọn ẹ ṣe ara gírí, mo ti ṣẹgun ayé.” +Ṣugbọn mo ti sọ gbogbo nǹkan wọnyi fun yín, kí ẹ lè ranti pé mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, nígbà tí ó bá yá, tí wọn bá ń ṣe é si yín.“N kò sọ àwọn nǹkan wọnyi fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀ nítorí mo wà lọ́dọ̀ yín. +Ṣugbọn nisinsinyii mò ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Ẹnìkankan ninu yín kò wí pé, ‘Níbo ni ò ń lọ?’ +Ṣugbọn ìbànújẹ́ kún ọkàn yín nítorí mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín. +Sibẹ òtítọ́ ni mo sọ fun yín. Ó sàn fun yín pé kí n lọ. Nítorí bí n kò bá lọ, Alátìlẹ́yìn tí mo wí kò ní wá sọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn bí mo bá lọ, n óo rán an si yín. +Nígbà tí ó bá dé, yóo fi han aráyé pé wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀, ati nípa òdodo, ati nípa ìdájọ́ Ọlọrun. +Wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé wọn kò gbà mí gbọ́. +Adura Jesu. +Lẹ́yìn tí Jesu ti sọ ọ̀rọ̀ wọnyi tán, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó ní, “Baba, àkókò náà dé! Jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára Ọmọ, kí ògo Ọmọ náà lè hàn lára rẹ. +Ohun gbogbo tí mo ní, tìrẹ ni; ohun gbogbo tí ìwọ náà sì ní, tèmi ni. Wọ́n ti jẹ́ kí ògo mi yọ. +Èmi kò ní sí ninu ayé mọ́, ṣugbọn àwọn wà ninu ayé. Èmi ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan. +Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ wọn, mo fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́. Mo pa wọ́n mọ́, ọ̀kan ninu wọn kò ṣègbé àfi ọmọ ègbé, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ. +Ṣugbọn nisinsinyii mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Mò ń sọ ọ̀rọ̀ wọnyi ninu ayé, kí wọ́n lè ní ayọ̀ mi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ninu ọkàn wọn. +Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn. Ayé kórìíra wọn nítorí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi náà kì í ti ṣe tíí ayé. +N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o mú wọn kúrò ninu ayé. Ẹ̀bẹ̀ mi ni pé kí o pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ Èṣù. +Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í tíí ṣe ti ayé. +Fi òtítọ́ yà wọ́n sí mímọ́ fún ara rẹ; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. +Gẹ́gẹ́ bí o ti rán mi sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni mo rán wọn lọ sinu ayé. +Nítorí tiwọn ni mo ṣe ya ara mi sí mímọ́, kí àwọn fúnra wọn lè di mímọ́ ninu òtítọ́. +Gẹ́gẹ́ bí o ti fún un ní àṣẹ lórí ẹ̀dá gbogbo, pé kí ó lè fi ìyè ainipẹkun fún gbogbo ẹni tí o ti fún un. +“N kò gbadura fún àwọn wọnyi nìkan. Ṣugbọn mo tún ń gbadura fún àwọn tí yóo gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn, +pé kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan. Mo gbadura pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ninu mi, tí èmi náà sì wà ninu rẹ, kí àwọn náà lè wà ninu wa, kí ayé lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. +Ògo tí o fi fún mi ni mo fi fún wọn, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan; +èmi ninu wọn ati ìwọ ninu mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo, kí ayé lè mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́, ati pé o fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́ràn mi. +“Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fi fún mi wà pẹlu mi níbi tí èmi gan-an bá wà, kí wọ́n lè máa wo ògo tí o ti fi fún mi, nítorí o ti fẹ́ràn mi kí á tó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀. +Baba mímọ́, ayé kò mọ̀ ọ́, ṣugbọn èmi mọ̀ ọ́, ó ti yé àwọn wọnyi pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. +Mo ti mú kí orúkọ rẹ hàn sí wọn, n óo sì tún fihàn, kí ìfẹ́ tí o fẹ́ mi lè wà ninu wọn, kí èmi náà sì wà ninu wọn.” +Ìyè ainipẹkun náà ni pé, kí wọ́n mọ̀ ọ́, ìwọ Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo, kí wọ́n sì mọ Jesu Kristi ẹni tí o rán níṣẹ́. +Èmi ti fi ògo fún ọ ninu ayé, mo ti parí iṣẹ́ tí o fún mi ṣe. +Nisinsinyii, Baba, jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára mi; àní kí irú ògo tí mo ti ní pẹlu rẹ kí a tó dá ayé tún hàn lára mi. +“Mo ti fi orúkọ rẹ han àwọn eniyan tí o fún mi ninu ayé. Tìrẹ ni wọ́n, ìwọ ni o wá fi wọ́n fún mi. Wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. +Nisinsinyii ó ti yé wọn pé láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo tí o fún mi ti wá. +Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o fún mi ni mo ti fún wọn. Wọ́n ti gba àwọn ọ̀rọ̀ náà, ó ti wá yé wọn pé nítòótọ́, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni mo ti wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́. +“Àwọn ni mò ń gbadura fún, n kò gbadura fún aráyé; ṣugbọn mò ń gbadura fún àwọn tí o ti fún mi, nítorí tìrẹ ni wọ́n. +Àwọn Ọ̀tá Mú Jesu. +Lẹ́yìn tí Jesu ti gba adura yìí tán, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí òdìkejì àfonífojì odò Kidironi. Ọgbà kan wà níbẹ̀. Ó wọ inú ọgbà náà, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. +Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ó ní idà kan fà á yọ, ó bá ṣá ẹrú Olórí Alufaa, ó gé e létí ọ̀tún. Maliku ni orúkọ ẹrú náà. +Jesu bá sọ fún Peteru pé, “Ti idà rẹ bọ inú àkọ̀. Àbí kí n má jẹ ìrora ńlá tí Baba ti yàn fún mi ni?” +Ni àwọn ọmọ-ogun ati ọ̀gágun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn Juu bá mú Jesu, wọ́n dè é, +wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Anasi tíí ṣe baba iyawo Kayafa, tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ní ọdún náà. +Kayafa yìí ni ó fi ìmọ̀ràn fún àwọn Juu pé ó sàn kí ẹnìkan kú fún gbogbo eniyan. +Ṣugbọn Simoni Peteru ń tẹ̀lé Jesu pẹlu ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn. Ọmọ-ẹ̀yìn keji yìí jẹ́ ẹni tí Olórí Alufaa mọ̀. +Ṣugbọn Peteru dúró lóde lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn keji tí Olórí Alufaa mọ̀ jáde, ó bá mú Peteru wọ agbo-ilé. +Nígbà náà ni ọmọge tí ó ń ṣọ́nà sọ fún Peteru pé, “Ṣé kì í ṣe pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkunrin yìí ni ọ́?”Peteru dáhùn pé, “Rárá o!” +Àwọn ẹrú ati àwọn ẹ̀ṣọ́ jọ dúró ní àgbàlá, wọ́n ń yáná tí wọ́n fi èédú dá, nítorí òtútù mú. Peteru náà dúró lọ́dọ̀ wọn, òun náà ń yáná. +Olórí Alufaa bi Jesu nípa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati nípa ẹ̀kọ́ rẹ̀. +Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, mọ ibẹ̀, nítorí ìgbà pupọ ni Jesu ti máa ń lọ sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. +Jesu dá a lóhùn pé, “Ní gbangba ni èmi tí máa ń bá aráyé sọ̀rọ̀. Ninu ilé ìpàdé ati ninu Tẹmpili ni èmi tí máa ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo, níbi tí gbogbo àwọn Juu ń péjọ sí, n kò sọ ohunkohun níkọ̀kọ̀. +Kí ni ò ń bi mí sí? Bi àwọn tí ó ti gbọ́ ohun tí mo sọ fún wọn; wọ́n mọ ohun tí mo sọ.” +Bí ó ti sọ báyìí tán ni ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó dúró níbẹ̀ bá gbá Jesu létí, ó ní, “Olórí Alufaa ni o dá lóhùn bẹ́ẹ̀!” +Jesu dá a lóhùn pé, “Bí burúkú ni mo bá sọ, wí ohun tí ó burú níbẹ̀ kí ayé gbọ́. Tí ó bá jẹ́ rere ni mo sọ, kí ló dé tí o fi lù mí?” +Nígbà náà ni Anasi fi Jesu ranṣẹ ní dídè sí Kayafa, Olórí Alufaa. +Simoni Peteru wà níbi tí ó dúró, tí ó ń yáná. Wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé kì í ṣe pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni ọ́?”Ó sẹ́, ó ní, “Rárá o!” +Ọ̀kan ninu àwọn ẹrú Olórí Alufaa, tí ó jẹ́ ẹbí ẹni tí Peteru gé létí bi Peteru pé, “Ǹjẹ́ n kò rí ọ ninu ọgbà pẹlu rẹ̀?” +Peteru tún sẹ́. Lẹsẹkẹsẹ àkùkọ kan bá kọ. +Lẹ́yìn náà wọ́n mú Jesu kúrò níwájú Kayafa lọ sí ààfin. Ilẹ̀ ti mọ́ ní àkókò yìí. Àwọn fúnra wọn kò wọ inú ààfin, kí wọn má baà di aláìmọ́, kí wọn baà lè jẹ àsè Ìrékọjá. +Pilatu bá jáde lọ sọ́dọ̀ wọn lóde, ó bi wọ́n pé, “Ẹ̀sùn wo ni ẹ fi kan ọkunrin yìí?” +Judasi bá mú àwọn ọmọ-ogun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n wá sibẹ pẹlu ògùṣọ̀ ati àtùpà ati àwọn ohun ìjà. +Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí ọkunrin yìí kò bá ṣe nǹkan burúkú ni, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́ fún ìdájọ́.” +Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un lọ, kí ẹ ṣe ìdájọ́ fún un bí òfin yín.”Ṣugbọn àwọn Juu sọ fún un pé, “A kò ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́ ikú fún ẹnikẹ́ni.” +Gbolohun yìí jáde kí ọ̀rọ̀ Jesu lè ṣẹ nígbà tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóo kú. +Pilatu bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?” +Jesu dáhùn pé, “O wí èyí fúnrarẹ ni àbí ẹlòmíràn ni ó sọ bẹ́ẹ̀ fún ọ nípa mi?” +Pilatu dáhùn pé, “Èmi í ṣe Juu bí? Àwọn eniyan rẹ ati àwọn olórí alufaa ni wọ́n fà ọ́ wá sọ́dọ̀ mi. Kí ni o ṣe?” +Jesu dá a lóhùn pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé yìí ni ìjọba mi, àwọn iranṣẹ mi ìbá jà; àwọn Juu kì bá tí lè mú mi. Ṣùgbọ́n ìjọba mi kì í ṣe ti ìhín.” +Pilatu wá bi í pé, “Èyí ni pé ọba ni ọ́?”Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí pé Ọba ni mí. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe bí mi, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe wá sáyé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe ti òtítọ́ yóo gbọ́ ohùn mi.” +Pilatu bi í pé, “Kí ni òtítọ́?”Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó tún jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn Juu, ó sọ fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ. +Ṣugbọn ẹ ní àṣà kan, pé kí n dá ẹnìkan sílẹ̀ fun yín ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá. Ṣé ẹ fẹ́ kí n dá ‘Ọba àwọn Juu’ sílẹ̀ fun yín?” +Nígbà tí Jesu rí ohun gbogbo tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun, ó jáde lọ pàdé wọn, ó bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?” +Wọ́n tún kígbe pé, “Òun kọ́! Baraba ni kí o dá sílẹ̀!” (Ọlọ́ṣà paraku ni Baraba yìí.) +Wọ́n dá a lóhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”Ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí.”Judasi, ẹni tí ó fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, dúró pẹlu wọn. +Nígbà tí ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, ni wọ́n bá ṣubú lulẹ̀. +Ó tún bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”Wọ́n dáhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.” +Jesu wí fún wọn pé, “Mo sọ fun yín pé èmi gan-an nìyí. Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ̀ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọnyi máa lọ.” +(Kí ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Ọ̀kan kan kò ṣègbé ninu àwọn tí o ti fi fún mi.”) +Wọ́n Kan Jesu Mọ́ Agbelebu. +Nígbà náà ni Pilatu mú Jesu, ó ní kí wọ́n nà án. +Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò dá lóhùn? O kò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti dá ọ sílẹ̀, mo sì ní àṣẹ láti kàn ọ́ mọ́ agbelebu?” +Jesu dá a lóhùn pé, “O kò ní àṣẹ lórí mi àfi èyí tí a ti fi fún ọ láti òkè wá. Nítorí náà, ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pọ̀jù ni ẹni tí ó fà mí lé ọ lọ́wọ́.” +Láti ìgbà náà ni Pilatu ti ń wá ọ̀nà láti dá Jesu sílẹ̀. Ṣugbọn àwọn Juu ń kígbe pé, “Bí o bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari, gbogbo ẹni tí ó bá fi ara rẹ̀ jọba lòdì sí Kesari.” +Nígbà tí Pilatu gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó mú Jesu jáde, ó wá jókòó lórí pèpéle ìdájọ́ níbìkan tí wọn ń pè ní “Pèpéle olókùúta,” tí ń jẹ́ “Gabata” ní èdè Heberu. +Ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ fún Àjọ̀dún Ìrékọjá ni ọjọ́ náà. Ó tó nǹkan agogo mejila ọ̀sán. Pilatu sọ fún àwọn Juu pé, “Ọba yín nìyí!” +Ṣugbọn àwọn Juu kígbe pé, “Mú un kúrò! Mú un kúrò! Kàn án mọ́ agbelebu!”Pilatu sọ fún wọn pé, “Kí n kan ọba yín mọ́ agbelebu?”Àwọn olórí alufaa dá a lóhùn pé, “A kò ní ọba lẹ́yìn Kesari.” +Pilatu bá fa Jesu fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu.Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu. +Ó ru agbelebu rẹ̀ jáde lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ “Ibi Agbárí,” tí wọn ń pè ní “Gọlgọta” ní èdè Heberu. +Níbẹ̀ ni wọ́n ti kàn án mọ́ agbelebu, òun ati àwọn meji kan, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ òsì, Jesu wá wà láàrin. +Pilatu kọ àkọlé kan, ó fi sórí agbelebu. Ohun tí ó kọ sórí rẹ̀ ni pé, “Jesu ará Nasarẹti, ọba àwọn Juu.” +Àwọn ọmọ-ogun bá fi ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún hun adé, wọ́n fi dé e lórí; wọn wọ̀ ọ́ ní ẹ̀wù kan bíi ẹ̀wù àlàárì, +Pupọ ninu àwọn Juu ni ó ka àkọlé náà ní èdè Heberu ati ti Latini ati ti Giriki. +Àwọn olórí alufaa àwọn Juu sọ fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ ọ́ pé ‘Ọba àwọn Juu,’ ṣugbọn kọ ọ́ báyìí: ‘Ó ní: èmi ni ọba àwọn Juu.’ ” +Ṣugbọn Pilatu dá wọn lóhùn pé, “Ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́ ná.” +Nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ agbelebu tán, àwọn ọmọ-ogun pín àwọn aṣọ rẹ̀ sí ọ̀nà mẹrin, wọ́n mú un ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ó wá tún ku àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọ̀tẹ́lẹ̀ yìí kò ní ojúùrán, híhun ni wọ́n hun ún láti òkè dé ilẹ̀. +Wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Ẹ má jẹ́ kí á ya á, gègé ni kí ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ láti mọ ti ẹni tí yóo jẹ́.” Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé,“Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn,wọ́n ṣẹ́ gègé lórí ẹ̀wù mi.”Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn ọmọ-ogun sì ṣe. +Ìyá Jesu ati arabinrin ìyá rẹ̀ ati Maria aya Kilopasi ati Maria Magidaleni dúró lẹ́bàá agbelebu Jesu. +Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ ati ọmọ-ẹ̀yìn tí ó fẹ́ràn tí wọ́n dúró, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obinrin, wo ọmọ rẹ.” +Ó bá sọ fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ.” Láti ìgbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà ti mú ìyá Jesu lọ sílé ara rẹ̀. +Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Jesu mọ̀ pé ohun gbogbo ti parí, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ, ó ní, “Òùngbẹ ń gbẹ mí.” +Àwo ọtí kan wà níbẹ̀. Wọ́n bá fi kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí náà, wọ́n fi sórí ọ̀pá gígùn kan, wọ́n nà án sí i lẹ́nu. +wọ́n wá ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbá a létí. +Lẹ́yìn tí Jesu ti gba ọtí náà tán, ó wí pé, “Ó ti parí!”Lẹ́yìn náà ó tẹrí ba, ó bá dákẹ́. +Nítorí ọjọ́ náà jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ Àjọ̀dún Ìrékọjá, kí òkú má baà wà lórí agbelebu ní Ọjọ́ Ìsinmi, àwọn Juu bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí wọ́n dá àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ní ojúgun, kí wọ́n gbé wọn kúrò lórí agbelebu nítorí pé Ọjọ́ Ìsinmi pataki ni Ọjọ́ Ìsinmi náà. +Àwọn ọmọ-ogun bá lọ, wọ́n dá ekinni-keji àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu Jesu lójúgun. +Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n rí i pé ó ti kú, nítorí náà wọn kò dá a lójúgun. +Ṣugbọn ọmọ-ogun kan fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, ẹ̀jẹ̀ ati omi bá tú jáde. +(Ẹni tí ọ̀rọ̀ yìí ṣe ojú rẹ̀ ni ó jẹ́rìí, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀, ó mọ̀ pé òtítọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́.) +Gbogbo èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Kò sí egungun rẹ̀ kan tí wọ́n ṣẹ́.” +Ìwé Mímọ́ tún wí níbòmíràn pé, “Wọn yóo wo ẹni tí wọ́n fi ọ̀kọ̀ gún.” +Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, Josẹfu ará Arimatia bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí òun gbé òkú Jesu lọ. Josẹfu yìí jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó fara pamọ́ nítorí ó bẹ̀rù àwọn Juu. Pilatu bá fún un ní àṣẹ láti gbé òkú Jesu. Ó bá lọ gbé e. +Nikodemu, tí ó fòru bojú lọ sọ́dọ̀ Jesu nígbà kan rí, mú àdàlú òróró olóòórùn dídùn olówó iyebíye oríṣìí meji wá, wíwúwo rẹ̀ tó ọgbọ̀n kilogiramu. +Pilatu tún jáde lọ sóde, ó sọ fún àwọn Juu pé, “Mò ń mú un tọ̀ yín bọ̀ wá sóde, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí i pé ó jẹ̀bi ohunkohun.” +Wọ́n fi òróró yìí tọ́jú òkú Jesu, wọ́n bá wé e ní aṣọ-ọ̀gbọ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà ìsìnkú àwọn Juu. +Ọgbà kan wà níbi tí wọ́n ti kan Jesu mọ́ agbelebu. Ibojì titun kán wà ninu ọgbà náà, wọn kò ì tíì sin òkú kankan sinu rẹ̀ rí. +Wọ́n tẹ́ òkú Jesu sibẹ, nítorí ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn Juu ni, ati pé ibojì náà súnmọ́ tòsí. +Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.” +Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ rí i, wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!”Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ kàn án mọ́ agbelebu, nítorí ní tèmi, n kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ.” +Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “A ní òfin kan, nípa òfin náà, ikú ni ó tọ́ sí i, nítorí ó fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.” +Nígbà tí Pilatu gbọ́ gbolohun yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á. +Ó bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Níbo ni o ti wá?”Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn. +Jesu Lọ sí Ibi Igbeyawo Kan ní Kana. +Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n ń ṣe igbeyawo kan ní Kana, ìlú kan ní Galili. Ìyá Jesu wà níbẹ̀. +Ó ní, “Ọtí tí ó bá dùn ni gbogbo eniyan kọ́ ń gbé kalẹ̀. Nígbà tí àwọn eniyan bá ti mu ọtí yó tán, wọn á wá gbé ọtí èyí tí kò dára tóbẹ́ẹ̀ wá. Ṣugbọn ìwọ fi àtàtà ọtí yìí pamọ́ di àkókò yìí!” +Èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Èyí gbé ògo rẹ̀ yọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́. +Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapanaumu, òun, ìyá rẹ̀, àwọn arakunrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ bíi mélòó kan. +Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá àwọn Juu, Jesu gòkè lọ sí Jerusalẹmu. +Ó rí àwọn tí ń ta mààlúù, aguntan, ati ẹyẹlé ninu àgbàlá Tẹmpili, ati àwọn tí ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó. +Jesu bá fi okùn kan ṣe ẹgba, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé gbogbo wọn jáde kúrò ninu àgbàlá Ilé Ìrúbọ. Ó lé àwọn tí ń ta aguntan ati mààlúù jáde. Ó da gbogbo owó àwọn onípàṣípààrọ̀ nù, ó sì ti tabili wọn ṣubú. +Ó sọ fún àwọn tí ń ta ẹyẹlé pé, “Ẹ gbé gbogbo nǹkan wọnyi kúrò níhìn-ín, ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!” +Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti àkọsílẹ̀ kan tí ó kà báyìí, “Ìtara ilé rẹ ti jẹ mí lógún patapata.” +Àwọn Juu wá bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ óo fihàn wá gẹ́gẹ́ bíi ìdí tí o fi ń ṣe nǹkan wọnyi?” +Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá wó Tẹmpili yìí, èmi yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.” +Wọ́n pe Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi igbeyawo náà. +Àwọn Juu wí fún un pé, “Aadọta ọdún ó dín mẹrin ni ó gbà wá láti kọ́ Tẹmpili yìí, ìwọ yóo wá kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta?” +Ṣugbọn ara rẹ̀ ni ó ń sọ̀rọ̀ bá, tí ó pè ní Tẹmpili. +Nítorí náà, nígbà tí a ti jí i dìde kúrò ninu òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti pé ó ti sọ èyí fún wọn, wọ́n wá gba Ìwé Mímọ́ gbọ́ ati ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ. +Nígbà tí Jesu wà ní agbègbè Jerusalẹmu ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, ọpọlọpọ eniyan gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n ṣe akiyesi àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe. \ No newline at end of file