diff --git "a/yorubaCorpus/Ycorpusss_7.txt" "b/yorubaCorpus/Ycorpusss_7.txt" new file mode 100644--- /dev/null +++ "b/yorubaCorpus/Ycorpusss_7.txt" @@ -0,0 +1,7586 @@ +Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Má ṣe dí mààlúù tí ó ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ati pé, “Owó oṣù òṣìṣẹ́ tọ́ sí i.” +Bí ẹnìkan bá fi ẹ̀sùn kan àgbàlagbà, má ṣe kà á sí àfi tí ẹlẹ́rìí meji tabi mẹta bá wà. +Mú àwọn àgbà obinrin bí ìyá; mú àwọn ọ̀dọ́ obinrin bí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ pẹlu ìwà mímọ́ ní ọ̀nà gbogbo. +Bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wí ní gbangba, kí ẹ̀rù lè ba àwọn yòókù. +Mo sọ fún ọ, níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, ati àwọn angẹli tí Kristi ti yàn, pé kí o pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́; má ṣe ojuṣaaju. +Má fi ìwàǹwára gbé ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni lórí láti fi jẹ oyè ninu ìjọ, má sì di alábàápín ninu ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn. Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ mọ́. +Má máa mu omi nìkan, ṣugbọn máa lo waini díẹ̀, nítorí inú tí ń yọ ọ́ lẹ́nu ati nítorí àìsàn tí ó máa ń ṣe ọ́ nígbà gbogbo. +Àwọn kan wà tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn hàn sí gbogbo eniyan, àwọn adájọ́ ti mọ̀ wọ́n kí wọ́n tó mú wọn dé kọ́ọ̀tù. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn a máa pẹ́ kí ó tó hàn sóde. +Bákan náà ni, iṣẹ́ rere a máa hàn sí gbogbo eniyan. Bí wọn kò bá tilẹ̀ tíì hàn, wọn kò ṣe é bò mọ́lẹ̀ títí. +Bu ọlá fún àwọn opó tí wọ́n jẹ́ alailẹnikan. +Ṣugbọn bí opó kan bá ní àwọn ọmọ tabi àwọn ọmọ-ọmọ, wọ́n gbọdọ̀ kọ́ láti ṣe ìtọ́jú ìdílé wọn, kí wọ́n san pada ninu ohun tí àwọn òbí wọn ti ṣe fún wọn. Èyí ni ohun tí ó dára lójú Ọlọrun. +Ṣugbọn ẹni tí ó bá jẹ́ opó nítòótọ́, tí kò ní ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, Ọlọrun nìkan ni ó ń wò, tí ó ń bẹ̀, tí ó ń gbadura sí tọ̀sán-tòru. +Ṣugbọn opó tí ó bá ń gbádùn ara rẹ̀ káàkiri ti kú sáyé. +Àwọn ohun tí o óo máa pa láṣẹ nìyí, kí wọ́n lè jẹ́ aláìlẹ́gàn. +Bí ẹnìkan kò bá pèsè fún àwọn ẹbí rẹ̀, pataki jùlọ fún àwọn ìdílé rẹ̀, olúwarẹ̀ ti lòdì sí ẹ̀sìn igbagbọ wa, ó sì burú ju alaigbagbọ lọ. +Má kọ orúkọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ bí opó àfi ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá dín ní ọgọta ọdún, tí ó sì jẹ́ aya ọkọ kan, +Iṣẹ́ sí Àwọn tí ó Gbàgbọ́. +Àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àjàgà ẹrú níláti rí i pé wọ́n ń bu ọlá fún àwọn ọ̀gá wọn ní ọ̀nà gbogbo, kí àwọn eniyan má baà sọ̀rọ̀ ìṣáátá sí orúkọ Ọlọrun ati ẹ̀kọ́ onigbagbọ. +Ìfẹ́ owó ni ìpìlẹ̀ gbogbo nǹkan burúkú. Èyí ni àwọn mìíràn ń lépa tí wọ́n fi ṣìnà kúrò ninu igbagbọ, tí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn fa ọpọlọpọ ìbànújẹ́ fún ara wọn. +Ṣugbọn ìwọ eniyan Ọlọrun, sá fún nǹkan wọnyi. Máa lépa òdodo, ati ìfọkànsìn Ọlọrun, igbagbọ, ìfẹ́, ìfaradà, ati ìwà pẹ̀lẹ́. +Máa ja ìjà rere ti igbagbọ. Di ìyè ainipẹkun mú. Ohun tí Ọlọrun pè ọ́ fún nìyí, òun sì ni ẹ̀rí rere tí o fi ẹnu ara rẹ jẹ́ níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí. +Mo pá a láṣẹ fún ọ níwájú Ọlọrun tí ó fi ẹ̀mí sinu gbogbo ohun alààyè, ati níwájú Kristi Jesu tí òun náà jẹ́rìí rere níwájú Pọntiu Pilatu, +pé kí o mú gbogbo àṣẹ tí o ti gbà ṣẹ láìsí àléébù ati láìsí ẹ̀gàn títí Oluwa wa Jesu Kristi yóo fi farahàn. +Ọlọrun yóo mú ìfihàn yìí wá ní àkókò tí ó bá wù ú, òun ni aláṣẹ kanṣoṣo, Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn oluwa; +òun nìkan tí kì í kú, tí ó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí eniyan kò lè súnmọ́, tí ẹnikẹ́ni kò rí rí, tí eniyan kò tilẹ̀ lè rí. Tirẹ̀ ni ọlá ati agbára tí kò lópin. Amin. +Mo pa á láṣẹ fún àwọn ọlọ́rọ̀ ayé yìí, pé kí wọ́n má ṣe ní ọkàn gíga. Bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n má ṣe gbára lé ọrọ̀ tí kò lágbẹkẹ̀lé, ṣugbọn kí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun tí ó ń fún wa ní gbogbo ọrọ̀ fún ìgbádùn wa. +Kí wọn máa ṣe rere, kí wọn jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu iṣẹ́ rere, kí wọn fẹ́ràn láti máa ṣe ọrẹ ati láti máa mú ninu ohun ìní wọn fún àwọn ẹlòmíràn, +kí wọ́n lè ní ìṣúra fún ara wọn tí yóo jẹ́ ìpìlẹ̀ rere fún ẹ̀yìn ọ̀la, kí ọwọ́ wọn lè tẹ ìyè tòótọ́. +Àwọn ẹrú tí wọ́n ní ọ̀gá onigbagbọ kò gbọdọ̀ sọ ara wọn di ẹgbẹ́ ọ̀gá wọn, wọn ìbáà jẹ́ ará ninu Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n níláti sìn wọ́n tara-tara, nítorí àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ fún jẹ́ arakunrin ninu igbagbọ ati ìfẹ́.Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa fi kọ́ àwọn eniyan, kí o sì máa fi gbà wọ́n níyànjú. +Timoti mi ọ̀wọ́n, pa ìṣúra tí a fi fún ọ mọ́. Di etí rẹ sí àwọn ọ̀rọ̀ játijàti tí kò ṣeni ní anfaani ati àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn kan ń ṣì pè ní ọ̀rọ̀ ọgbọ́n. Àṣìpè ni, nítorí pé wọ́n kún fún àwọn ẹ̀kọ́ tí ó lòdì sí ara wọn. +Àwọn mìíràn tí wọ́n tẹ̀lé irú ọ̀nà yìí ti ṣìnà kúrò ninu igbagbọ.Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wà pẹlu yín. +Bí ẹnìkan bá ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ mìíràn, tí kò mọ ẹ̀kọ́ tí ó yè, ẹ̀kọ́ ti Oluwa wa Jesu Kristi, ati ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí ó pé, +ìgbéraga ti sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di aṣiwèrè, kò sì mọ nǹkankan. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ óo fẹ́ràn láti máa ṣe òfintótó ọ̀ràn, ati iyàn jíjà, àwọn ohun tí ó ń mú owú-jíjẹ, ìjà, ìsọkúsọ, ìfura burúkú, +ati àríyànjiyàn wá. Nǹkan wọnyi wọ́pọ̀ láàrin àwọn tí orí wọn ti kú, tí wọ́n ti yapa kúrò ní ọ̀nà òtítọ́. Wọ́n rò pé nítorí èrè ni eniyan fi ń ṣe ẹ̀sìn. +Òtítọ́ ni pé èrè ńlá wà ninu jíjẹ́ olùfọkànsìn, tí eniyan bá ní ìtẹ́lọ́rùn. +Nítorí a kò mú ohunkohun wá sinu ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè mú ohunkohun kúrò ninu rẹ̀. +Bí a bá ti ní oúnjẹ ati aṣọ, kí á ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu wọn. +Àwọn tí wọn ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa ṣubú sinu ìdánwò, tàkúté a sì mú wọn. Wọn a máa lépa ọpọlọpọ nǹkan tí kò mú ọgbọ́n wá ati àwọn nǹkan tí ó lè pa eniyan lára, irú nǹkan tí ó ti mú kí àwọn mìíràn jìn sinu ọ̀fìn ikú ati ìparun. +Ẹ̀kọ́ Burúkú ati Ọ̀rọ̀ Tòótọ́. +Solomoni, ọmọ Dafidi, fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, OLUWA Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀, ó sì sọ ọ́ di ẹni ńlá. +Fún mi ní ọgbọ́n ati ìmọ̀ tí n óo fi máa ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi, nítorí pé ó ṣòro fún ẹnikẹ́ni láti ṣe àkóso àwọn eniyan rẹ tí wọ́n pọ̀ tó báyìí.” +Ọlọrun dá Solomoni lóhùn pé, “Nítorí pé irú èrò yìí ló wà lọ́kàn rẹ, ati pé o kò sì tọrọ nǹkan ìní, tabi ọrọ̀, ọlá, tabi ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ, o kò tilẹ̀ tọrọ ẹ̀mí gígùn, ṣugbọn ọgbọ́n ati ìmọ̀ ni o tọrọ, láti máa ṣe àkóso àwọn eniyan mi tí mo fi ọ́ jọba lé lórí, +n óo fún ọ ní ọgbọ́n ati ìmọ̀; n óo sì fún ọ ní ọrọ̀, nǹkan ìní, ati ọlá, irú èyí tí ọba kankan ninu àwọn tí wọ́n ti jẹ ṣiwaju rẹ kò tíì ní rí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní sí èyí tí yóo jẹ lẹ́yìn rẹ tí yóo ní irú rẹ̀.” +Solomoni kúrò ní àgọ́ ìpàdé tí ó wà ní ibi ìrúbọ ní Gibeoni, ó wá sí Jerusalẹmu, ó sì jọba lórí Israẹli. +Solomoni kó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin jọ; àwọn kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ egbeje (1,400) àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ ẹgbaafa (12,000); ó kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Jerusalẹmu. +Fadaka ati wúrà tí ọba kójọ, pọ̀ bíi òkúta ní Jerusalẹmu, igi kedari sì pọ̀ bí igi sikamore tí ó wà ní Ṣefela, ní ẹsẹ̀ òkè Juda. +Láti Ijipti ati Kue ni Solomoni ti ń kó ẹṣin wá, àwọn oníṣòwò tí wọn ń ṣiṣẹ́ fún un ni wọ́n ń ra àwọn ẹṣin náà wá láti Kue. +Àwọn oníṣòwò a máa ra kẹ̀kẹ́ ogun kan ni ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli fadaka wá fún Solomoni láti Ijipti, wọn a sì máa ra ẹṣin kan ní aadọjọ (150) ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Àwọn náà ni wọ́n sì ń bá a tà wọ́n fún àwọn ọba ilẹ̀ Hiti ati ti ilẹ̀ Siria. +Solomoni bá gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀: àwọn balogun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati ti ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, àwọn adájọ́, àwọn olórí ní Israẹli ati àwọn baálé baálé. +Solomoni ati àwọn tí wọ́n péjọ lọ sí ibi gíga tí ó wà ní Gibeoni, nítorí pé àgọ́ ìpàdé Ọlọrun tí Mose, iranṣẹ OLUWA, pa ninu aginjù wà níbẹ̀. +Ṣugbọn Dafidi ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọrun wá láti Kiriati Jearimu sinu àgọ́ tí ó pa fún un ní Jerusalẹmu. +Pẹpẹ bàbà tí Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri ṣe, wà níbẹ̀ níwájú àgọ́ OLUWA. Solomoni ati àwọn eniyan rẹ̀ sin OLUWA níbẹ̀. +Ó lọ sí ìdí pẹpẹ bàbà tí ó wà níwájú OLUWA ninu àgọ́ àjọ, ó sì fi ẹgbẹrun (1,000) ẹran rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀. +Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun fara han Solomoni, ó wí fún un pé “Bèèrè ohun tí o bá fẹ́ kí n fún ọ.” +Solomoni dá Ọlọrun lóhùn, ó ní “O ti fi ìfẹ́ ńlá tí kìí yẹ̀ han Dafidi, baba mi, o sì ti fi mí jọba nípò rẹ̀. +OLUWA, Ọlọrun, mú ìlérí tí o ṣe fún Dafidi, baba mi, ṣẹ nisinsinyii, nítorí pé o ti fi mí jọba lórí àwọn eniyan tí wọ́n pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀. +Solomoni Ọba Gbadura fún Ọgbọ́n. +Rehoboamu lọ sí Ṣekemu, nítorí pé gbogbo Israẹli ti péjọ sibẹ láti fi jọba. +Àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé, “Lọ sọ fún wọn pé, ‘Ìka ọwọ́ mi tí ó kéré jù yóo tóbi ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ. +Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn tèmi yóo tún wúwo ju ti baba mi lọ. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi ta yín.’ ” +Ní ọjọ́ kẹta, Jeroboamu pẹlu àwọn ọmọ Israẹli bá pada wá sọ́dọ̀ Rehoboamu, gẹ́gẹ́ bí àdéhùn wọn. +Ọba kọ ìmọ̀ràn àwọn àgbà, ó gbójú mọ́ wọn, +ó sọ̀rọ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí àwọn ọ̀dọ́ fún un, ó ní, “Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn èmi óo tún fi kún àjàgà náà. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi máa ta yín.” +Ọba kò gbọ́ ti àwọn eniyan náà, nítorí pé ọwọ́ Ọlọrun ni àyípadà yìí ti wá, kí ó lè mú ohun tí ó ní kí wolii Ahija, ará Ṣilo, sọ fún Jeroboamu, ọmọ Nebati, ṣẹ. +Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé Rehoboamu kò gbọ́ tiwọn, wọ́n dáhùn pé,“Kí ló kàn wá pẹlu ilé Dafidi?Kí ló pa wá pọ̀ pẹlu ọmọ Jese?Ẹ pada sinu àgọ́ yín, ẹ̀yin ọmọ IsraẹliDafidi, fọwọ́ mú ilé rẹ.”Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lọ sí ilé wọn, +ṣugbọn Rehoboamu jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé Juda. +Ọba rán Hadoramu tí ó jẹ́ olórí àwọn akóniṣiṣẹ́ sí àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa. Rehoboamu ọba bá yára bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sá àsálà lọ sí Jerusalẹmu. +Láti ìgbà náà lọ ni àwọn ọmọ Israẹli ti ń bá ilé Dafidi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí. +Nígbà tí Jeroboamu, ọmọ Nebati, gbọ́, ó pada wá láti Ijipti, níbi tí ó ti sá lọ fún Solomoni. +Àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ranṣẹ sí i, òun ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sọ́dọ̀ Rehoboamu, wọ́n wí fún un pé, +“Àjàgà tí baba rẹ gbé bọ̀ wá lọ́rùn wúwo, ṣugbọn nisinsinyii, dín wahala tí baba rẹ fi wá ṣe kù, kí o sì sọ àjàgà wa di fúfúyẹ́, a óo sì máa sìn ọ́.” +Rehoboamu bá dáhùn pé, “Ẹ pada wá gbọ́ èsì lẹ́yìn ọjọ́ mẹta.” Àwọn eniyan náà bá lọ. +Rehoboamu bá lọ jíròrò pẹlu àwọn àgbààgbà Israẹli tí wọ́n bá baba rẹ̀ ṣiṣẹ́ nígbà ayé rẹ̀, ó ní, “Ẹ fún mi ní ìmọ̀ràn, irú èsì wo ni ó yẹ kí n fún àwọn eniyan wọnyi?” +Wọ́n gbà á ní ìmọ̀ràn pé, “Bí o bá ṣe dáradára sí àwọn eniyan wọnyi, tí o bá ṣe ohun tí ó tẹ́ wọn lọ́rùn, tí o sì sọ̀rọ̀ dáradára fún wọn, wọn yóo máa sìn ọ́ títí lae.” +Ṣugbọn Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn àwọn àgbà. Ó lọ jíròrò pẹlu àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀, tí wọn ń bá a ṣiṣẹ́, ó bi wọ́n pé, +“Kí ni èsì tí ó yẹ kí n fún àwọn tí wọ́n sọ fún mi pé kí n sọ àjàgà tí baba mi gbé bọ àwọn lọ́rùn di fúfúyẹ́?” +Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Àríwá Dìtẹ̀. +Nígbà tí Rehoboamu dé Jerusalẹmu, ó kó ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) àwọn akọni ọmọ ogun jọ láti inú ẹ̀yà Juda ati Bẹnjamini, láti bá àwọn ọmọ Israẹli jagun, kí ó lè fi ipá gba ìjọba rẹ̀ pada. +Sora, Aijaloni ati Heburoni. Àwọn ni ìlú olódi ní Juda ati Bẹnjamini. +Ó tún àwọn ìlú olódi ṣe, wọ́n lágbára, níbẹ̀ ni ó fi àwọn olórí ogun sí, ó sì kó ọpọlọpọ oúnjẹ, epo ati ọtí waini pamọ́ sibẹ. +Ó kó ọ̀kọ̀ ati apata sinu gbogbo wọn, ó sì fi agbára kún agbára wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe fi ọwọ́ mú Juda ati Bẹnjamini. +Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli sì fara mọ́ Rehoboamu. Gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí wọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. +Àwọn ọmọ Lefi fi ilẹ̀ wọn sílẹ̀ ati ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n kó wá sí Juda, ati Jerusalẹmu; nítorí pé Jeroboamu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lé wọn jáde, wọn kò jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí alufaa Ọlọrun. +Ó yan àwọn alufaa ti ara rẹ̀ fún ibi ìrúbọ ati fún ilé ère ewúrẹ́ ati ti ọmọ aguntan tí ó gbé kalẹ̀. +Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ sin Ọlọrun Israẹli tọkàntọkàn láti inú olukuluku ẹ̀yà Israẹli, tẹ̀lé àwọn alufaa wá sí Jerusalẹmu láti ṣe ìrúbọ sí OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. +Wọ́n sọ ìjọba Juda di alágbára, wọ́n sì ṣe alátìlẹ́yìn fún Rehoboamu ọmọ Solomoni fún ọdún mẹta; wọ́n ń rìn ní ìlànà Dafidi ati ti Solomoni ní gbogbo ìgbà náà. +Rehoboamu fẹ́ Mahalati, ọmọ Jerimotu, ọmọ Dafidi, ìyá rẹ̀ ni Abihaili, ọmọ Eliabu, ọmọ Jese. +Iyawo Rehoboamu yìí bí ọmọkunrin mẹta fún un; wọ́n ń jẹ́: Jeuṣi, Ṣemaraya ati Sahamu. +Ṣugbọn OLUWA sọ fún wolii Ṣemaaya, eniyan Ọlọrun pé, +Lẹ́yìn náà, ó tún fẹ́ Maaka, ọmọ Absalomu; òun bí ọmọkunrin mẹrin fún un; wọ́n ń jẹ́ Abija, Atai, Sisa ati Ṣelomiti. +Maaka, ọmọ Absalomu ni Rehoboamu fẹ́ràn jùlọ ninu àwọn iyawo rẹ̀. Àwọn mejidinlogun ni ó gbé ní iyawo, o sì ní ọgọta obinrin mìíràn. Ó bí ọmọkunrin mejidinlọgbọn ati ọgọta ọmọbinrin. +Ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ tí ń jẹ́ Abija ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù lọ. Ó yàn án láti jẹ́ ọba lẹ́yìn tí òun bá kú. +Ó dọ́gbọ́n fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe olórí káàkiri, ó pín wọn káàkiri jákèjádò ilẹ̀ Juda ati Bẹnjamini ní àwọn ìlú alágbára. Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n ṣe aláìní. Ó sì fẹ́ iyawo fún gbogbo wọn. +“Sọ fún Rehoboamu ọmọ Solomoni, ọba Juda, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé Juda ati Bẹnjamini pé, +OLUWA ní, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ bá àwọn arakunrin yín jà. Kí olukuluku yín pada sí ilé rẹ̀ nítorí èmi ni mo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ó ṣẹlẹ̀.’ ” Wọ́n gbọ́ràn sí OLUWA lẹ́nu, wọ́n pada, wọn kò sì lọ bá Jeroboamu jagun mọ́. +Rehoboamu ń gbé Jerusalẹmu, ó kọ́ àwọn ìlú ààbò wọnyi sí Juda: +Bẹtilẹhẹmu, Etamu, ati Tekoa; +Betisuri, Soko, ati Adulamu; +Gati, Mareṣa, ati Sifi; +Adoraimu, Lakiṣi, ati Aseka; +Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣemaaya. +Láìpẹ́, lẹ́yìn tí Rehoboamu fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ tí ó di alágbára, òun ati àwọn eniyan rẹ̀ kọ òfin OLUWA sílẹ̀. +Nítorí náà, Rehoboamu ṣe apata bàbà dípò wọn, ó sì fi wọ́n sábẹ́ àkóso olùṣọ́ ààfin. +Nígbàkúùgbà tí ọba bá lọ sí ilé OLUWA, olùṣọ́ ààfin á ru apata náà ní iwájú rẹ̀, lẹ́yìn náà yóo kó wọn pada sí ibi tí wọ́n kó wọn pamọ́ sí. +Nítorí pé Rehoboamu ronupiwada, OLUWA yí ibinu rẹ̀ pada, kò pa á run patapata mọ́. Nǹkan sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ dáradára ní ilẹ̀ Juda. +Rehoboamu fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní Jerusalẹmu, agbára rẹ̀ sì pọ̀ sí i. Ọmọ ọdún mọkanlelogoji ni nígbà tí ó jọba. Ó jọba fún ọdún mẹtadinlogun ní Jerusalẹmu, ìlú tí OLUWA yàn láàrin àwọn ẹ̀yà yòókù, pé kí wọ́n ti máa sin òun. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Naama, ará Amoni. +Rehoboamu ṣe nǹkan burúkú, nítorí pé kò fi ọkàn sí ati máa rìn ní ìlànà OLUWA. +Gbogbo ohun tí Rehoboamu ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn wolii Ṣemaaya, ati sinu ìwé Ido aríran. Nígbà gbogbo ni ogun máa ń wà láàrin Rehoboamu ati Jeroboamu. +Nígbà tí Rehoboamu kú, wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, níbi ibojì àwọn baba rẹ̀. Abija ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Nígbà tí ó di ọdún karun-un ìjọba rẹ̀, Ọlọrun fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí aiṣootọ rẹ̀. Ṣiṣaki ọba Ijipti gbógun ti Jerusalẹmu pẹlu ẹgbẹfa (1,200) kẹ̀kẹ́ ogun, +ati ọ̀kẹ́ mẹta (60,000) ẹlẹ́ṣin, ati ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e láti Ijipti. Àwọn ará Libia, àwọn ará Sukiimu, ati àwọn ará Etiopia wà ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀. +Ó gba gbogbo ìlú olódi Juda títí ó fi dé Jerusalẹmu. +Lẹ́yìn náà, wolii Ṣemaaya lọ bá Rehoboamu ati gbogbo àwọn olóyè Juda, tí wọ́n ti péjọ sí Jerusalẹmu lórí ọ̀rọ̀ Ṣiṣaki ọba Ijipti. Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA ní ẹ ti kọ òun sílẹ̀, nítorí náà ni òun ṣe fi yín lé Ṣiṣaki lọ́wọ́.” +Àwọn ìjòyè ní Israẹli ati Rehoboamu ọba bá wí pẹlu ìtẹríba pé, “Olódodo ni Ọlọrun.” +Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti ronupiwada, ó sọ fún wolii Ṣemaaya pé, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, òun kò ní pa wọ́n run mọ́, ṣugbọn òun óo gbà wọ́n sílẹ̀ díẹ̀. Òun kò ní fi agbára lo Ṣiṣaki láti rọ̀jò ibinu òun sórí Jerusalẹmu. +Sibẹsibẹ wọn yóo jẹ́ ẹrú rẹ̀, kí wọ́n lè mọ ìyàtọ̀ ninu pé kí wọ́n sin òun OLUWA, ati kí wọ́n sin ìjọba àwọn ilẹ̀ mìíràn. +Ṣiṣaki bá gbógun ti Jerusalẹmu, ó kó gbogbo ìṣúra ilé OLUWA lọ, ati ti ààfin ọba patapata, ati apata wúrà tí Solomoni ṣe. +Àwọn Ará Ijipti Gbógun ti Juda. +Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Jeroboamu ni Abija jọba ní ilẹ̀ Juda. +“Ṣugbọn ní tiwa, OLUWA Ọlọrun ni à ń sìn; a kò kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ọmọ Aaroni ni àwọn alufaa wa, àwọn ọmọ Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. +Ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́ ni wọ́n ń rú ẹbọ sísun, tí wọ́n sì ń sun turari. Wọ́n ń fi àkàrà ìfihàn sórí tabili wúrà. Ní alaalẹ́, wọ́n ń tan fìtílà wúrà lórí ọ̀pá fìtílà rẹ̀; nítorí àwa ń ṣe ohun tí Ọlọrun wa pa láṣẹ fún wa, ṣugbọn ẹ̀yin ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. +Ọlọrun wà pẹlu wa, òun fúnrarẹ̀ ni aṣaaju wa. Àwọn alufaa rẹ̀ wà níhìn-ín láti fun fèrè láti pè wá kí á gbógun tì yín. Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ má ṣe bá OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín jà, nítorí ẹ kò ní borí.” +Ṣugbọn Jeroboamu ti rán ọ̀wọ́ ọmọ ogun kan lọ láti kọlu àwọn ọmọ ogun Juda látẹ̀yìn. Àwọn ọmọ ogun Jeroboamu wà níwájú àwọn ọmọ ogun Juda, àwọn tí ó rán tí wọ́n sápamọ́ sì wà lẹ́yìn wọn. +Nígbà tí Juda rí i pé ogun wà níwájú ati lẹ́yìn wọn, wọ́n ké pe OLUWA, àwọn alufaa sì fọn fèrè ogun. +Àwọn ọmọ ogun Juda hó ìhó ogun, bí wọ́n sì ti kígbe ni Ọlọrun ṣẹgun Jeroboamu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli fún Abija ati àwọn ọmọ ogun Juda. +Àwọn ọmọ ogun Israẹli bá sá níwájú àwọn ọmọ ogun Juda, Ọlọrun sì fi wọ́n lé àwọn ọmọ ogun Juda lọ́wọ́. +Abija ati àwọn ọmọ ogun Juda pa àwọn ọmọ ogun Israẹli ní ìpakúpa, tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀kẹ́ mẹẹdọgbọn (500,000) fi kú ninu àwọn akọni ọmọ ogun Israẹli. +Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda ṣe tẹ orí àwọn ọmọ Israẹli ba tí wọ́n sì ṣẹgun wọn, nítorí pé àwọn ọmọ Juda gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. +Abija lé Jeroboamu, ó sì gba ìlú Bẹtẹli, ati Jeṣana, ati Efuroni ati àwọn ìletò tí ó yí wọn ká lọ́wọ́ rẹ̀. +Ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Mikaya, ọmọ Urieli ará Gibea.Nígbà kan, ogun bẹ́ sílẹ̀ láàrin Abija ati Jeroboamu. +Jeroboamu kò sì lè gbérí ní àkókò Abija. Nígbà tí ó yá Ọlọrun lu Jeroboamu pa. +Ṣugbọn agbára Abija bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ síi. Iyawo mẹrinla ni ó ní; ó sì bí ọmọkunrin mejilelogun ati ọmọbinrin mẹrindinlogun. +Gbogbo nǹkan yòókù ti Abija ṣe ní àkókò ìjọba rẹ̀, ati ohun tí ó sọ, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn wolii Ido. +Abija kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) akọni ọmọ ogun jọ láti bá Jeroboamu jagun. Jeroboamu náà kó ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) akọni ọmọ ogun jọ. +Abija gun orí òkè Semaraimu tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu lọ. Ó kígbe lóhùn rara, ó ní: “Gbọ́ mi, ìwọ Jeroboamu ati gbogbo ẹ̀yin eniyan Israẹli, +ṣé ẹ ẹ̀ mọ̀ pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ti fi iyọ̀ bá Dafidi dá majẹmu ayérayé pé àtìrandíran rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí Israẹli títí lae? +Sibẹsibẹ, Jeroboamu, ọmọ Nebati, iranṣẹ Solomoni, ọmọ Dafidi, dìde, ó ṣọ̀tẹ̀ sí Solomoni, oluwa rẹ̀. +Ó sì lọ kó àwọn jàǹdùkú ati àwọn aláìníláárí eniyan kan jọ, wọ́n pe Rehoboamu ọmọ Solomoni níjà. Rehoboamu jẹ́ ọmọde nígbà náà, kò sì ní ìrírí tó láti dojú ìjà kọ wọ́n. +Nisinsinyii, ẹ rò pé ẹ lè dojú ìjà kọ ìjọba OLUWA, tí ó gbé lé àwọn ọmọ Dafidi lọ́wọ́; nítorí pé ẹ pọ̀ ní iye ati pé ẹ ní ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí Jeroboamu fi wúrà ṣe tí ó pè ní ọlọrun yín? +Ẹ ti lé àwọn alufaa OLUWA kúrò lọ́dọ̀ yín: àwọn ọmọ Aaroni, ati àwọn ọmọ Lefi. Ẹ yan alufaa mìíràn dípò wọn bí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ti ṣe. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá ti mú akọ mààlúù tabi aguntan meje wá, ẹ̀ ń yà á sí mímọ́ fún iṣẹ́ alufaa àwọn oriṣa tí kì í ṣe Ọlọrun. +Ogun láàrin Abija ati Jeroboamu. +Nígbà tí Abija ọba kú, wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní àkókò rẹ̀, alaafia wà ní ilẹ̀ náà fún ọdún mẹ́wàá. +Asa jáde lọ láti bá a jà. Olukuluku tẹ́ ibùdó ogun rẹ̀ sí àfonífojì Sefata ní Mareṣa. +Asa ké pe OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kò sí olùrànlọ́wọ́ tí ó dàbí rẹ nítorí pé o lè ran àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lágbára lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn tí wọ́n lágbára. Ràn wá lọ́wọ́, OLUWA Ọlọrun wa, nítorí pé ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé. Ní orúkọ rẹ ni a jáde láti wá bá ogun ńlá yìí jà. OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun wa, má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣẹgun rẹ.” +Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe ṣẹgun àwọn ará Etiopia fún Asa ati àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Etiopia sì sá. +Asa ati àwọn ogun rẹ̀ lé wọn títí dé Gerari. Ọpọlọpọ àwọn ará Etiopia sì kú tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè gbá ara wọn jọ mọ́; wọn sì parun patapata níwájú OLUWA ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Juda sì kó ọpọlọpọ ìkógun. +Wọ́n run gbogbo ìlú tí ó wà ní agbègbè Gerari, nítorí pé ẹ̀rù OLUWA ba àwọn ará ibẹ̀. Wọ́n fi ogun kó gbogbo àwọn ìlú náà nítorí pé ìkógun pọ̀ ninu wọn. +Wọ́n wó gbogbo àgọ́ àwọn tí ń sin mààlúù, wọ́n sì kó ọpọlọpọ aguntan ati ràkúnmí wọn pada sí Jerusalẹmu. +Asa ṣe ohun tí ó dára, tí ó tọ́, tí ó sì dùn mọ́ OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ó mú inú Ọlọrun dùn. +Ó kó àwọn pẹpẹ àjèjì ati àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn kúrò, ó wó àwọn òpó oriṣa wọn lulẹ̀, ó sì fọ́ ère Aṣera. +Ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Juda láti wá ojurere OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn ati láti pa òfin rẹ̀ mọ́. +Ó kó gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ ati àwọn pẹpẹ tí wọ́n ti ń sun turari ní gbogbo àwọn ìlú Juda jáde. Alaafia sì wà ní àkókò ìjọba rẹ̀. +Ó kọ́ àwọn ìlú olódi sí ilẹ̀ Juda nítorí pé alaafia wà ní gbogbo ilẹ̀ náà. Ní gbogbo ọdún rẹ̀ kò sí ogun, nítorí OLUWA fún wọn ní alaafia. +Ó bá sọ fún gbogbo ọmọ ilẹ̀ Juda pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọ́ àwọn ìlú wọnyi, kí á mọ odi yí wọn ká pẹlu ilé ìṣọ́, kí á kan ìlẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè wọn, kí á sì fi àwọn ọ̀pá ìdábùú sí wọn. Ìkáwọ́ wa ni gbogbo ilẹ̀ náà wà, nítorí pé à ń ṣe ìfẹ́ OLUWA Ọlọrun wa. A ti wá ojurere rẹ̀, ó sì fún wa ní alaafia ní gbogbo ọ̀nà.” Wọ́n kọ́ àwọn ìlú náà, wọ́n sì ń ní ìtẹ̀síwájú. +Asa ọba ní ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) ọmọ ogun ní ilẹ̀ Juda, tí wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọ̀kọ̀ ati ọ̀kẹ́ mẹrinla (280,000) láti Bẹnjamini tí wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọrun. Gbogbo wọn ni a ti kọ́ ní ogun jíjà tí wọ́n sì jẹ́ akọni. +Sera, ará Etiopia, gbógun tì wọ́n pẹlu ẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun (1,000,000) ọmọ ogun ati ọọdunrun (300) kẹ̀kẹ́ ogun. Wọ́n sì jagun títí dé Mareṣa. +Asa Ọba Ṣẹgun Àwọn Ará Sudani. +Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Asaraya ọmọ Odedi. +Wọ́n péjọ ní Jerusalẹmu ní oṣù kẹta ọdún kẹẹdogun ìjọba Asa. +Wọ́n mú ẹẹdẹgbẹrin (700) mààlúù ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan ninu ìkógun tí wọ́n kó, wọ́n fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun baba wọn. +Wọ́n dá majẹmu pé àwọn yóo máa sin OLUWA Ọlọrun baba àwọn tọkàntọkàn àwọn; +ati pé ẹnikẹ́ni tí kò bá sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, ìbáà ṣe àgbà tabi ọmọde, ọkunrin tabi obinrin, pípa ni àwọn yóo pa á. +Wọ́n fi igbe búra ní orúkọ OLUWA pẹlu ariwo ati fèrè. +Inú gbogbo Juda sì dùn sí ẹ̀jẹ́ náà, nítorí pé tọkàntọkàn ni wọ́n fi jẹ́ ẹ. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń sin Ọlọrun. Ọlọrun gba ìsìn wọn, ó sì fún wọn ní alaafia ní gbogbo ọ̀nà. +Asa ọba, yọ Maaka ìyá rẹ̀ àgbà pàápàá kúrò ní ipò ìyá ọba, nítorí pé ó gbẹ́ ère ìríra kan fún oriṣa Aṣera. Asa wó ère náà lulẹ̀, ó gé e wẹ́lẹwẹ̀lẹ, ó sì dáná sun ún ní odò Kidironi. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Asa kò wó gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ palẹ̀ ní ilẹ̀ Israẹli, sibẹsibẹ kò ní ẹ̀bi ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. +Ó kó àwọn nǹkan tí Abija, baba rẹ̀, ti yà sí mímọ́ fún Ọlọrun lọ sinu tẹmpili pẹlu gbogbo nǹkan tí òun pàápàá ti yà sí mímọ́: fadaka, wúrà, ati àwọn ohun èlò. +Kò sí ogun mọ́ rárá títí tí ó fi di ọdún karundinlogoji ìjọba Asa. +Ó lọ pàdé Asa, ó wí fún un pé, “Gbọ́ mi, ìwọ Asa, ati gbogbo ẹ̀yin ọmọ Juda ati ti Bẹnjamini, OLUWA wà pẹlu yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin náà bá wà pẹlu rẹ̀. Bí ẹ bá wá a, ẹ óo rí i. Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun náà yóo kọ̀ yín sílẹ̀. +Ọjọ́ pẹ́, tí Israẹli ti wà láìní Ọlọrun òtítọ́, wọn kò ní alufaa tí ń kọ́ ni, wọn kò sì ní òfin. +Ṣugbọn nígbà tí ìyọnu dé, wọ́n yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Wọ́n wá OLUWA, wọ́n sì rí i. +Ní àkókò náà, kò sí ìbàlẹ̀ ọkàn fún àwọn tí wọn ń jáde ati àwọn tí wọ́n ń wọlé, nítorí ìdààmú ńlá dé bá àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà. +Orílẹ̀-èdè kan ń pa ekeji run, ìlú kan sì ń pa ekeji rẹ́, nítorí Ọlọrun mú oniruuru ìpọ́njú bá wọn. +Ṣugbọn, ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ mọ́kàn le, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó rẹ̀ yín, nítorí iṣẹ́ yín yóo ní èrè.” +Nígbà tí Asa gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Asaraya ọmọ Odedi sọ, ó mọ́kàn le. Ó kó gbogbo ère kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Juda ati gbogbo ilẹ̀ Bẹnjamini ati ní gbogbo àwọn ìlú tí wọ́n gbà ní agbègbè olókè Efuraimu. Ó tún pẹpẹ OLUWA tí ó wà níwájú yàrá àbáwọlé ilé OLUWA ṣe. +Ó kó gbogbo àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Bẹnjamini jọ, ati àwọn tí wọ́n wá láti Efuraimu, Manase ati Simeoni, tí wọ́n jẹ́ àlejò láàrin wọn. Nítorí pé ọpọlọpọ eniyan láti ilẹ̀ Israẹli ni wọ́n ti sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọ́n rí i pé OLUWA Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀. +Asa Ṣe Àtúnṣe. +Ní ọdún kẹrindinlogoji ìjọba Asa, ní ilẹ̀ Juda, Baaṣa ọba Israẹli gbógun ti Juda, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi Rama láti dí ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ilẹ̀ Juda, kí ẹnikẹ́ni má baà lè lọ sí ọ̀dọ̀ Asa, ọba Juda, kí àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ má sì lè jáde. +Ọ̀rọ̀ yìí mú kí inú bí Asa sí wolii Hanani, ó sì kan ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ninu túbú, nítorí inú bí i sí i fún ohun tí ó sọ. Asa ọba fi ìyà jẹ àwọn kan ninu àwọn ará ìlú ní àkókò náà. +Gbogbo nǹkan tí Asa ọba ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati Israẹli. +Ní ọdún kọkandinlogoji ìjọba Asa, àrùn burúkú kan mú un lẹ́sẹ̀, àrùn náà pọ̀ pupọ. Sibẹsibẹ, ninu àìsàn náà kàkà kí ó ké pe OLUWA fún ìwòsàn, ọ̀dọ̀ àwọn oníṣègùn ni ó lọ. +Asa kú ní ọdún kọkanlelogoji ìjọba rẹ̀. +Wọ́n sin ín sinu ibojì òkúta tí ó gbẹ́ fúnrarẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n tẹ́ ẹ sórí àkéte, tí ó kún fún oniruuru turari tí àwọn tí wọ́n ń ṣe turari ṣe. Wọ́n sì dá iná ńlá kan láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. +Nítorí náà, Asa kó fadaka ati wúrà láti ilé ìṣúra ilé OLUWA ati láti ààfin ranṣẹ sí Benhadadi, ọba Siria tí ó ń gbé Damasku, ó ranṣẹ sí i pé: +“Jẹ́ kí àjọṣepọ̀ wà láàrin wa gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láàrin àwọn baba wa. Fadaka ati wúrà yìí ni mo fi ta ọ́ lọ́rẹ; pa majẹmu tí ó wà láàrin ìwọ ati Baaṣa ọba Israẹli tì, kí ó baà lè kó ogun rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi.” +Benhadadi gba ọ̀rọ̀ Asa, ó bá rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jáde láti lọ gbógun ti àwọn ìlú Israẹli. Wọ́n ṣẹgun Ijoni, Dani, Abeli Maimu ati gbogbo ìlú tí wọ́n kó ìṣúra pamọ́ sí ní ilẹ̀ Nafutali. +Nígbà tí Baaṣa gbọ́ ohun tí ń ṣẹlẹ̀, ó dáwọ́ odi Rama tí ó ń mọ dúró. +Asa bá kó àwọn eniyan jọ jákèjádò Juda, wọ́n lọ kó òkúta ati pákó tí Baaṣa fi ń kọ́ Rama, wọ́n lọ fi kọ́ Geba ati Misipa. +Nígbà náà ni Hanani aríran, wá sọ́dọ̀ Asa, ọba Juda, ó wí fún un pé, “Nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, dípò kí o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun rẹ, àwọn ogun Siria ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ. +Ṣebí ogun Etiopia ati Libia lágbára gidigidi? Ṣebí wọ́n ní ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹlẹ́ṣin? Ṣugbọn nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn. +Nítorí ojú OLUWA ń lọ síwá sẹ́yìn ní gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn fún àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí i. Ìwà òmùgọ̀ ni èyí tí o hù yìí; nítorí pé láti ìsinsìnyìí lọ nígbàkúùgbà ni o óo máa jagun.” +Ìyọnu De bá Israẹli. +Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbáradì láti dojú ìjà kọ Israẹli. +OLUWA da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí Juda ká, wọn kò sì gbógun ti Jehoṣafati. +Àwọn kan ninu àwọn ará Filistia mú ẹ̀bùn ati fadaka wá fún Jehoṣafati gẹ́gẹ́ bíi ìṣákọ́lẹ̀. Àwọn ará Arabia náà sì mú ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) àgbò, ati ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) òbúkọ wá. +Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣafati ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i, ó kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ ati àwọn ìlú tí wọn ń kó ìṣúra pamọ́ sí ní Juda; +ó ní ilé tí wọn ń kó nǹkan pamọ́ sí ní àwọn ìlú ńláńlá Juda.Ó sì ní àwọn akọni ọmọ ogun ní Jerusalẹmu. +Iye àwọn ọmọ ogun tí ó kó jọ nìyí gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: Adinai ni olórí ogun ẹ̀yà Juda, ó sì ní ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) akọni ọmọ ogun lábẹ́ rẹ̀. +Olórí ogun tí ó pọwọ́ lé e ni Jehohanani, ó ní ọ̀kẹ́ mẹrinla (280,000) ọmọ ogun lábẹ́ rẹ̀. +Olórí ogun kẹta ni Amasaya, ọmọ Sikiri, ẹni tí ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ OLUWA, ó ní ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) akọni ọmọ ogun. +Àwọn olórí ogun láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini ni: Eliada, akọni ọmọ ogun, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn ọmọ ogun tí wọn ń lo apata ati ọrun ni wọ́n wà lábẹ́ rẹ̀. +Igbákejì ni Jehosabadi; òun náà ní ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) ọmọ ogun tí wọ́n ti dira ogun, lábẹ́ rẹ̀. +Gbogbo àwọn wọnyi ni wọ́n wà lábẹ́ ọba ní Jerusalẹmu, láìka àwọn tí ó fi sí àwọn ìlú olódi ní gbogbo ilẹ̀ Juda. +Ó kó àwọn ọmọ ogun sí gbogbo àwọn ìlú olódi Juda, ó yan olórí ogun fún wọn ní ilẹ̀ Juda ati ní ilẹ̀ Efuraimu tí Asa baba rẹ̀ gbà. +OLUWA wà pẹlu Jehoṣafati nítorí pé ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbà ọ̀dọ̀ Dafidi, baba rẹ̀; kò sì bọ oriṣa Baali. +Ṣugbọn ó ń sin Ọlọrun àwọn baba rẹ̀, ó pa òfin Ọlọrun mọ́, kò sì tẹ̀lé ìṣe àwọn ọmọ Israẹli. +Nítorí náà OLUWA fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ Juda sì ń san owó orí fún un. Nítorí náà ó di ọlọ́rọ̀ ati ọlọ́lá. +Ó fi ìgboyà rìn ní ọ̀nà OLUWA, ó wó gbogbo pẹpẹ oriṣa, ó sì gé àwọn ère Aṣera káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda. +Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó pe àwọn marun-un ninu àwọn ìjòyè rẹ̀: Benhaili, Ọbadaya, ati Sakaraya, Netaneli, ati Mikaya, ó rán wọn jáde láti máa kọ́ àwọn eniyan ní ilẹ̀ Juda. +Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wọn lọ ni: Ṣemaaya, Netanaya, ati Sebadaya; Asaheli, Ṣemiramotu, ati Jehonatani; Adonija, Tobija ati Tobadonija. Àwọn alufaa tí wọ́n tẹ̀lé wọn ni Eliṣama ati Jehoramu. +Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda pẹlu ìwé òfin lọ́wọ́ wọn, wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan. +Jehoṣafati di Ọba. +Nígbà tí Jehoṣafati ọba Juda di ọlọ́rọ̀ ati olókìkí, ó fẹ́ ọmọ Ahabu kí ó lè ní àjọṣepọ̀ pẹlu Ahabu. +Ọ̀kan ninu àwọn wolii tí à ń pè ní Sedekaya, ọmọ Kenaana ṣe àwọn ìwo irin kan, ó sì sọ fún Ahabu pé, “OLUWA ní, pẹlu àwọn ìwo wọnyi ni o óo fi bi àwọn ará Siria sẹ́yìn, títí tí o óo fi run wọ́n patapata.” +Àwọn wolii yòókù ń sọ bákan náà, wọ́n ń wí pé, “Lọ gbógun ti Ramoti Gileadi, o óo ṣẹgun. OLUWA yóo fi wọ́n lé ọba lọ́wọ́.” +Iranṣẹ tí ó lọ pe Mikaya sọ fún un pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ni gbogbo àwọn wolii ń sọ, pé ọba yóo ṣẹgun, ìwọ náà sọ bẹ́ẹ̀.” +Ṣugbọn Mikaya dáhùn pé, “Mo fi orúkọ OLUWA búra pé ohun tí Ọlọrun bá sọ fún mi pé kí n sọ ni n óo sọ.” +Nígbà tí ó dé iwájú Ahabu, Ahabu bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Mikaya, ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi tabi kí á má ṣe lọ?”Mikaya dáhùn pé, “Ẹ lọ gbógun tì í, OLUWA yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì ṣẹgun.” +Ṣugbọn Ahabu bi í pé, “Ìgbà mélòó ni mo níláti mú ọ búra pé kí o máa sọ òtítọ́ fún mi ní orúkọ OLUWA?” +Mikaya bá sọ pé, “Mo rí i tí gbogbo ọmọ ogun Israẹli fọ́n káàkiri lórí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA bá sọ pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí. Jẹ́ kí olukuluku máa lọ sí ilé rẹ̀ ní alaafia.’ ” +Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣé o ranti pé mo ti sọ pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún mi rí? Àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nìkan ni òun máa ń sọ.” +Mikaya bá dáhùn pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ! Mo rí OLUWA, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, àwọn ogun ọ̀run sì wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì rẹ̀. +OLUWA bèèrè pé, ‘Ta ni yóo lọ tan Ahabu, ọba Israẹli, kí ó lè lọ sí Ramoti Gileadi, kí ó sì kú níbẹ̀.’ Bí àwọn kan tí ń sọ nǹkankan, ni àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn. +Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Jehoṣafati lọ sí ìlú Samaria láti bẹ Ahabu wò. Láti dá Jehoṣafati lọ́lá pẹlu àwọn tí wọ́n bá a wá, Ahabu pa ọpọlọpọ aguntan ati mààlúù fún àsè. Ó rọ Jehoṣafati láti bá òun lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi. +Nígbà náà ni ẹ̀mí kan jáde, ó sì dúró níwájú OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tan Ahabu jẹ.’ OLUWA bá bèèrè pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o fẹ́ dá?’ +Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo lọ sọ gbogbo àwọn wolii Ahabu di wolii èké.’ OLUWA bá dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ ni kí o lọ tàn án jẹ, o óo sì ṣe àṣeyọrí, lọ ṣe bí o ti wí.’ ” +Mikaya ní, “OLUWA ni ó mú kí àwọn wolii rẹ wọnyi máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, ṣugbọn àjálù burúkú ni OLUWA ti pinnu pé yóo dé bá ọ.” +Nígbà náà ni Sedekaya, ọmọ Kenaana súnmọ́ Mikaya, ó gbá a létí, ó wí pé, “Nígbà wo ni ẹ̀mí OLUWA fi mí sílẹ̀ tí ó wá ń bá ọ sọ̀rọ̀?” +Mikaya dáhùn pé, “Ojú rẹ yóo já a ní ọjọ́ náà, nígbà tí o bá lọ sá pamọ́ sí kọ̀rọ̀ yàrá.” +Nígbà náà ni Ahabu ọba pàṣẹ pé kí wọ́n mú Mikaya lọ sọ́dọ̀ Amoni, gomina ìlú ati sọ́dọ̀ Joaṣi, ọmọ ọba, kí wọ́n sì sọ fún wọn pé: +Ẹ ju ọkunrin yìí sẹ́wọ̀n, kí wọ́n sì máa fún un ní omi ati burẹdi nìkan títí òun óo fi pada dé ní alaafia. +Mikaya dáhùn pé, “Tí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó sì tún sọ siwaju sí i pé, kí olukuluku fetí sí ohun tí òun wí dáradára. +Ahabu ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda lọ gbógun ti Ramoti Gileadi. +Ahabu sọ fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sógun yìí, n óo yí ara pada. Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Ọba Israẹli bá yíra pada, ó lọ sí ojú ogun. +Ahabu, ọba Israẹli bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé o óo bá mi lọ gbógun ti Ramoti Gileadi?”Jehoṣafati dáhùn pé, “Tìrẹ ni èmi ati àwọn eniyan mi, a óo bá ọ lọ jagun náà.” +Ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀gágun tí wọn ń ṣàkóso àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà bíkòṣe ọba Israẹli nìkan. +Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí Jehoṣafati, wọ́n rò pé ọba Israẹli ni, wọ́n bá yíjú sí i láti bá a jà. Jehoṣafati bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, OLUWA sì gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. +Nígbà tí àwọn ọ̀gágun náà rí i pé kì í ṣe Ahabu, ọba Israẹli, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ̀. +Ṣugbọn ọmọ ogun Siria kan déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí ìgbàyà ati ihamọra rẹ̀ ti pàdé. Ó bá kígbe sí ẹni tí ó ru ihamọra rẹ̀ pé, “Mo ti fara gbọgbẹ́, yipada kí o gbé mi kúrò lójú ogun.” +Ogun gbóná ní ọjọ́ náà, Ahabu ọba bá rá pálá dìde dúró, wọ́n fi ọwọ́ mú un ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó kọjú sí ogun Siria. Ṣugbọn nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, ó kú. +Ṣugbọn Jehoṣafati sọ fún ọba Israẹli pé, “Jẹ́ kí á kọ́kọ́ bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ná.” +Nítorí náà, Ahabu pe gbogbo àwọn Wolii jọ, gbogbo wọn jẹ́ irinwo (400). Ó bi wọ́n pé, “Ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi tabi kí á má lọ?”Wọ́n dáhùn pé, “Lọ gbógun tì í, Ọlọrun yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun.” +Ṣugbọn Jehoṣafati bèèrè lọ́wọ́ Ahabu pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA mìíràn mọ́ tí a lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀?” +Ahabu dáhùn pé, “Ó ku ọ̀kan tí à ń pè ní Mikaya, ọmọ Imila tí a lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ rere kan kò ti ẹnu rẹ̀ jáde sí mi rí, àfi kìkì burúkú.”Jehoṣafati dáhùn, ó ní, “Má sọ bẹ́ẹ̀.” +Nítorí náà, Ahabu ọba pe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ kí ó lọ pe Mikaya wá kíákíá. +Àwọn ọba mejeeji gúnwà lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà, ní àbáwọ bodè Samaria, gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. +Wolii Mikaya Kìlọ̀ fún Ahabu. +Jehoṣafati ọba Juda pada ní alaafia sí ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu. +Nígbàkúùgbà tí àwọn arakunrin yín bá mú ẹjọ́ wá siwaju yín láti ìlú kan, kì báà ṣe ti ìtàjẹ̀sílẹ̀, tabi ti nǹkan tí ó jẹ mọ́ òfin, tabi àṣẹ, tabi ìlànà, ẹ níláti ṣe àlàyé fún wọn kí wọ́n má baà jẹ̀bi níwájú OLUWA, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí ẹ̀yin náà ati àwọn arakunrin yín. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ gbọdọ̀ máa ṣe kí ẹ má baà jẹ̀bi. +Amaraya, olórí alufaa ni alabojuto yín ninu gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ OLUWA. Sebadaya, ọmọ Iṣimaeli, tí ó jẹ́ gomina ní Juda ni alabojuto lórí ọ̀rọ̀ ìlú, àwọn ọmọ Lefi yóo sì máa ṣe òjíṣẹ́ yín. Ẹ má bẹ̀rù. Kí OLUWA wà pẹlu ẹ̀yin tí ẹ dúró ṣinṣin.” +Ṣugbọn Jehu, aríran, ọmọ Hanani lọ pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Ṣé ó dára kí o máa ran eniyan burúkú lọ́wọ́, kí o fẹ́ràn àwọn tí wọ́n kórìíra OLUWA? Nítorí èyí, ibinu OLUWA ru sí ọ. +Sibẹsibẹ àwọn nǹkankan wà tí o ṣe tí ó dára, o run àwọn ère oriṣa Aṣera ní ilẹ̀ yìí, o sì ti ṣe ọkàn rẹ gírí láti tẹ̀lé Ọlọ́run.” +Jerusalẹmu ni Jehoṣafati ń gbé, ṣugbọn a máa lọ jákèjádò ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli, láti Beeriṣeba títí dé agbègbè olókè Efuraimu, a máa káàkiri láti yí wọn lọ́kàn pada sí OLUWA Ọlọrun baba wọn. +Ó yan àwọn adájọ́ ní gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Juda. +Ó kìlọ̀ fún wọn ó ní, “Ẹ ṣọ́ra gan-an, nítorí pé kì í ṣe eniyan ni ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún, OLUWA ni. Ẹ sì ranti pé OLUWA wà lọ́dọ̀ yín bí ẹ ti ń ṣe ìdájọ́. +Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì ṣọ́ra pẹlu àwọn nǹkan tí ẹ ó máa ṣe, nítorí pé OLUWA Ọlọrun wa kì í yí ìdájọ́ po, kì í ṣe ojuṣaaju, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.” +Jehoṣafati tún yan àwọn kan ní Jerusalẹmu ninu àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn alufaa ati àwọn baálé baálé ní Israẹli, láti máa fi òfin OLUWA ṣe ìdájọ́ ati láti máa yanjú ẹjọ́ tí kò bá di àríyànjiyàn. +Ó kìlọ̀ fún wọn, ó ní “Ohun tí ẹ gbọdọ̀ máa fi tọkàntọkàn ṣe, pẹlu ìbẹ̀rù OLUWA ati òtítọ́ nìyí: +Wolii Kan Bá Jehoṣafati Wí. +Solomoni ọba pinnu láti kọ́ tẹmpili níbi tí àwọn eniyan yóo ti máa sin OLUWA ati láti kọ́ ààfin fún ara rẹ̀. +N óo gbé ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n kori ọkà tí a ti lọ̀, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n baali, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati ọtí, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati òróró fún àwọn iranṣẹ rẹ tí wọn yóo gé àwọn igi náà, wọn óo gbé wọn wá fún ọ.” +Huramu, ọba Tire, bá dá èsì lẹta Solomoni pada, ó ní, “OLUWA fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀, ni ó ṣe fi ọ́ jọba lórí wọn.” +Ó tún fi kún un pé, “Ìy��n ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó dá ọ̀run ati ayé, tí ó fún Dafidi ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó sì ní òye ati ìmọ̀ láti kọ́ tẹmpili fún OLUWA ati láti kọ́ ààfin fún ara rẹ̀. +Mo ti rán Huramu sí ọ; ó mọṣẹ́, ó sì ní làákàyè. +Ará Dani ni ìyá rẹ̀, ṣugbọn ará Tire ni baba rẹ̀. Ó mọ iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ wúrà, ati ti fadaka, ti bàbà, ati ti irin; ó sì mọ òkúta, ati igi í gbẹ́. Ó mọ bí a tií ṣe iṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ elése àlùkò, aṣọ aláwọ̀ aró, àlàárì, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. Ó lè ṣe iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà, ó sì lè ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà tí wọ́n bá ní kí ó ṣe pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ tìrẹ, ati àwọn òṣìṣẹ́ oluwa mi, Dafidi, baba rẹ. +Nítorí náà, fi ọkà baali, òróró ati ọtí tí ìwọ oluwa mi ti ṣèlérí ranṣẹ sí èmi iranṣẹ rẹ. +A óo gé gbogbo igi tí o bá nílò ní Lẹbanoni, a óo sì tù wọ́n lójú omi wá sí Jọpa, láti ibẹ̀ ni ẹ lè wá kó wọn lọ sí Jerusalẹmu.” +Solomoni ka gbogbo àwọn àjèjì tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ meje, ó lé ẹgbaaje ati ẹgbẹta (153,600). +Ó yan ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbaarun (70,000) ninu wọn láti máa ru nǹkan ìkọ́lé, ó ní kí ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) eniyan máa la òkúta, kí ẹẹdẹgbaaji ó lé ẹgbẹta (3,600) jẹ́ alákòóso tí yóo máa kó wọn ṣiṣẹ́. +Ó kó ọ̀kẹ́ mẹta ati ẹgbaarun (70,000) àwọn òṣìṣẹ́ jọ láti máa ru àwọn nǹkan tí yóo fi kọ́lé, ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) àwọn òṣìṣẹ́ tí yóo máa fọ́ òkúta, ati ẹẹdẹgbaaji ó lé ẹgbẹta (3,600) eniyan láti máa bojútó àwọn òṣìṣẹ́. +Solomoni ranṣẹ sí Huramu, ọba Tire pé, “Máa ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Dafidi, baba mi, tí o kó igi kedari ranṣẹ sí i láti kọ́ ààfin rẹ̀. +Mo fẹ́ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun mi. Yóo jẹ́ ibi mímọ́ tí a ó ti máa sun turari olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀. A ó máa mú ẹbọ àkàrà ojoojumọ lọ sibẹ, a ó sì máa rú ẹbọ sísun níbẹ̀ láàárọ̀ ati lálẹ́; ati ní ọjọọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣooṣù, ati ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún OLUWA Ọlọrun wa, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli títí lae. +Ilé tí mo fẹ́ kọ́ yóo tóbi pupọ, nítorí pé Ọlọrun wa tóbi ju gbogbo oriṣa lọ. +Kò sí ẹni tí ó lè kọ́ ilé fún un, nítorí pé ọ̀run, àní ọ̀run tí ó ga jùlọ, kò le è gbà á. Kí ni mo jẹ́ tí n óo fi kọ́ ilé fún un, bíkòṣe pé kí n kọ́ ibi tí a óo ti máa sun turari níwájú rẹ̀? +Nítorí náà, fi ẹnìkan ranṣẹ sí mi, tí ó mọ̀ nípa iṣẹ́ wúrà, fadaka, bàbà, ati irin, ẹni tí ó lè ṣiṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ elése àlùkò, ati àlàárì, ati aṣọ aláwọ̀ aró, tí ó sì mọ̀ nípa iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà. Yóo wà pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ tí baba mi ti pèsè sílẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu mi ní Juda ati Jerusalẹmu. +Kó igi kedari, sipirẹsi ati aligumu ranṣẹ sí mi láti Lẹbanoni. Mo mọ̀ pé àwọn iranṣẹ rẹ mọ̀ bí wọ́n ṣe ń gé igi ní Lẹbanoni, àwọn iranṣẹ mi náà yóo sì wà pẹlu wọn, +láti tọ́jú ọpọlọpọ igi, nítorí pé ilé tí mo fẹ́ kọ́ yóo tóbi, yóo sì jọjú. +Ìpalẹ̀mọ́ fún Kíkọ́ Tẹmpili. +Lẹ́yìn èyí, àwọn ará Moabu, ati àwọn ará Amoni, ati díẹ̀ ninu àwọn ará Meuni kó ara wọn jọ láti bá Jehoṣafati jagun. +“Nisinsinyii, wo àwọn ọmọ ogun Amoni, ati ti Moabu ati ti Òkè Seiri, àwọn tí o kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli bá jà nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti, o kò jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n run. +Wò ó! Wọ́n ń fi burúkú san ire fún wa, wọ́n ń bọ̀ wá lé wa kúrò lórí ilẹ̀ rẹ, tí o fún wa bí ìní. +Ọlọrun wa, dá wọn lẹ́jọ́. Nítorí pé agbára wa kò tó láti dojú kọ ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun wọn tí wọn ń kó bọ̀ wá bá wa jà. A kò mọ ohun tí a lè ṣe, ìwọ ni a gbójú sókè tí à ń wò.” +Gbogbo àwọn ọkunrin Juda dúró níwájú OLUWA pẹlu àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, àwọn aya wọn ati àwọn ọmọ wọn. +Ẹ̀mí OLUWA bà lé Jahasieli, ọmọ Sakaraya, ọmọ Bẹnaya, ọmọ Jeieli, ọmọ Matanaya; ọmọ Lefi ni, láti inú ìran Asafu. Ó bá dìde dúró láàrin àwùjọ àwọn eniyan. +Ó ní, “Ẹ fetí sí mi, gbogbo ẹ̀yin ará Juda ati ti Jerusalẹmu ati ọba Jehoṣafati, OLUWA ní kí ẹ má fòyà, kí ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì nítorí ogun ńlá yìí; nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ ó ja ogun ńlá yìí, Ọlọrun ni. +Ní ọ̀la, ẹ kógun lọ bá wọn; wọn yóo gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Sisi wá, ẹ óo rí wọn ní òpin àfonífojì ní apá ìlà oòrùn aṣálẹ̀ Jerueli. +Ẹ kò ní jagun rárá, ẹ sá dúró ní ààyè yín, kí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo sì rí bí OLUWA yóo ti gba ẹ̀yin ará Juda ati Jerusalẹmu là. Ẹ má fòyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì, Ẹ lọ kò wọ́n lójú lọ́la, OLUWA yóo wà pẹlu yín.” +Jehoṣafati dojúbolẹ̀, gbogbo àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. +Ni àwọn ọmọ Lefi láti inú ìdílé Kohati ati ti Kora bá dìde, wọ́n gbóhùn sókè, wọ́n sì yin OLUWA Ọlọrun Israẹli. +Àwọn kan wá sọ fún Jehoṣafati pé ogun ńlá kan ń bọ̀ wá jà á láti Edomu ní òdìkejì òkun. Wọ́n sọ pé àwọn ọ̀tá náà ti dé Hasasoni Tamari, (tí a tún ń pè ní Engedi). +Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn eniyan náà lọ sí aṣálẹ̀ Tekoa. Bí wọ́n ti ń lọ, Jehoṣafati dúró, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, ẹ gba ohun tí àwọn wolii rẹ̀ wí gbọ́ pẹlu, ẹ óo sì ní ìṣẹ́gun.” +Nígbà tí Jehoṣafati bá àwọn eniyan rẹ̀ jíròrò tán, ó yan àwọn tí wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA; tí wọn yóo wọ aṣọ mímọ́, tí wọn yóo sì máa yìn ín bí wọn yóo ti máa lọ níwájú ogun, wọn yóo máa kọrin pé,“Ẹ yin OLUWA!Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ dúró laelae.” +Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọrin ìyìn, OLUWA gbẹ̀yìn yọ sí àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu ati ti Òkè Seiri tí wọ́n wá bá àwọn eniyan Juda jà, ó sì tú wọn ká. +Àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu gbógun ti àwọn ará Òkè Seiri wọ́n sì pa wọ́n run patapata. Lẹ́yìn náà, wọ́n dojú ìjà kọ ara wọn, wọ́n sì pa ara wọn run. +Nígbà tí ogun Juda dé ilé ìṣọ́ tí ó wà ninu aṣálẹ̀, wọ́n wo àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n sì rí i pé wọ́n ti kú sílẹ̀ lọ bẹẹrẹ; kò sí ẹni tí ó sá àsálà ninu wọn. +Nígbà tí Jehoṣafati ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ láti kó ìkógun, wọ́n rí ọpọlọpọ mààlúù, ati ẹrù aṣọ ati nǹkan ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye. Wọ́n kó wọn títí ó fi sú wọn. Odidi ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi kó ìkógun nítorí pé ó ti pọ̀ jù. +Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n péjọ ní àfonífojì Beraka. Ibẹ̀ ni wọ́n ti yin OLUWA. Nítorí náà ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí pe ibẹ̀ ní Beraka títí di òní olónìí. +Jehoṣafati kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu pẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun, nítorí pé OLUWA ti fún un ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. +Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, wọ́n wọ inú tẹmpili lọ, pẹlu ìró hapu, ati ti dùùrù ati ti fèrè. +Ẹ̀rù OLUWA ba ìjọba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbà tí wọ́n gbọ́ pé OLUWA bá àwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Israẹli jagun. +Ẹ̀rù ba Jehoṣafati gidigidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ojú OLUWA, ó kéde jákèjádò ilẹ̀ Juda pé kí wọ́n gbààwẹ̀. +Nítorí náà Jehoṣafati jọba ní alaafia, nítorí pé Ọlọrun fún un ní ìsinmi ní gbogbo àyíká rẹ̀. +Jehoṣafati jọba lórí Juda, ẹni ọdún marundinlogoji ni nígbà tí ó gorí oyè. Gbogbo ọdún tí ó lò lórí oyè jẹ́ ọdún mẹẹdọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Asuba, ọmọ Ṣilihi. +Ó ṣe dáradára gẹ́gẹ́ bí Asa, baba rẹ̀, ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA. +Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run; àwọn eniyan kò tíì máa fi tọkàntọkàn sin Ọlọrun àwọn baba ńlá wọn. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoṣafati ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn Jehu ọmọ Hanani, tí ó jẹ́ apá kan ìtàn àwọn ọba Israẹli. +Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Jehoṣafati, ọba Juda lọ darapọ̀ mọ́ Ahasaya, ọba Israẹli, tí ó jẹ́ eniyan burúkú. +Wọ́n jọ kan àwọn ọkọ̀ ojú omi tí yóo lọ sí ìlú Taṣiṣi. Wọ́n kan àwọn ọkọ̀ náà ní Esiongeberi. +Elieseri ọmọ Dodafahu, ará Mareṣa fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Jehoṣafati wí. Ó ní, “Nítorí pé o darapọ̀ mọ́ Ahasaya, OLUWA yóo ba ohun tí o ti ṣe tẹ́lẹ̀ jẹ́.” Gbogbo àwọn ọkọ̀ ojú omi náà rì, wọn kò sì lè lọ sí Taṣiṣi mọ́. +Àwọn eniyan péjọ láti gbogbo ìlú Juda, wọ́n wá bèèrè ìrànlọ́wọ́ OLUWA. +Jehoṣafati bá dìde dúró láàrin àwọn tí wọ́n ti Juda ati Jerusalẹmu wá sinu tẹmpili, níbi tí wọ́n péjọ sí níwájú gbọ̀ngàn tuntun, +ó ní, “OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa, ṣebí ìwọ ni Ọlọrun ọ̀run. Ìwọ ni o ni àkóso ìjọba gbogbo orílẹ̀-èdè. Agbára ati ipá wà ní ìkáwọ́ rẹ, kò sì sí ẹni tí ó tó dojú kọ ọ́. +Ṣebí ìwọ, Ọlọrun wa, ni o lé gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ kúrò fún àwa ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, tí o sì fi ilẹ̀ náà fún arọmọdọmọ Abrahamu, ọ̀rẹ́ rẹ, títí lae? +Wọ́n ti ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì ti kọ́ ibi mímọ́ sibẹ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, +nítorí pé tí ibi bá dé bá wa, tabi ìdájọ́, tabi àjàkálẹ̀ àrùn, tabi ìyàn, a óo dúró níwájú ilé yìí ati níwájú rẹ, nítorí orúkọ rẹ wà ninu ilé yìí. A óo ké pè ọ́ ninu ìyọnu wa, o óo gbọ́ tiwa, o óo sì gbà wá. +Wọ́n Gbógun ti Edomu. +Jehoṣafati kú, wọ́n sin ín pẹlu àwọn baba rẹ̀ ninu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Jehoramu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Láti ìgbà náà ni Edomu ti ń bá Juda ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí. Ní àkókò kan náà ni Libina ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, ó sì gba òmìnira nítorí pé Jehoramu ti fi ọ̀nà OLUWA àwọn baba rẹ̀ sílẹ̀. +Ó tilẹ̀ kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ káàkiri ní agbègbè olókè Juda. Ó fa àwọn ará Jerusalẹmu sinu aiṣododo, ó sì kó àwọn ọmọ Juda ṣìnà. +Elija wolii kọ ìwé kan sí Jehoramu, ohun tí ó kọ sinu ìwé náà nìyí: “Gbọ́ bí OLUWA Ọlọrun Dafidi, baba rẹ, ti wí; ó ní, nítorí pé o kò tọ ọ̀nà tí Jehoṣafati baba rẹ tọ̀, tabi ti Asa, baba baba rẹ. +Ṣugbọn ò ń hùwà bí àwọn ọba Israẹli, o sì ti fa àwọn Juda ati Jerusalẹmu sinu aiṣododo, bí ìdílé Ahabu ti ṣe fún Israẹli. Pataki jùlọ, o pa àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ baba rẹ, tí wọ́n tilẹ̀ sàn jù ọ́ lọ. +Wò ó, OLUWA yóo fi àjàkálẹ̀ àrùn ṣe àwọn eniyan rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn aya rẹ ati gbogbo ohun tí o ní. +Àrùn burúkú kan yóo kọlu ìwọ pàápàá, àrùn inú ni, yóo pọ̀, yóo sì pẹ́ lára rẹ títí tí ìfun rẹ yóo fi bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde.” +OLUWA mú kí inú àwọn ará Filistia ati ti àwọn ará Arabia, tí wọn ń gbé nítòsí àwọn ará Etiopia, ru sí Jehoramu. +Wọ́n dó ti Juda, wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n kó gbogbo ìṣúra tí ó wà ní ààfin lọ, pẹlu àwọn ọmọ Jehoramu ati àwọn iyawo rẹ̀. Kò ku ẹyọ ọmọ kan àfi èyí àbíkẹ́yìn tí ń jẹ́ Ahasaya. +Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, OLUWA fi àrùn inú kan tí kò ṣe é wò bá Jehoramu jà. +Lẹ́yìn ọdún keji tí àìsàn náà tí ń ṣe é, ìfun rẹ̀ tú síta, ó sì kú ninu ọpọlọpọ ìrora. Wọn kò dá iná ẹ̀yẹ fún un gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti máa ń ṣe níbi ìsìnkú àwọn baba rẹ̀. +Jehoramu ní arakunrin mẹfa, tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Jehoṣafati, orúkọ wọn ni, Asaraya, Jehieli, ati Sakaraya, Asaraya, Mikaeli ati Ṣefataya. +Ẹni ọdún mejilelọgbọn ni nígbà tí ó gorí oyè, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹjọ. Nígbà tí ó kú, kò sí ẹni tí ó sọkún, tabi tí ó ṣọ̀fọ̀ níbi òkú rẹ̀. Ìlú Dafidi ni wọ́n sin ín sí, ṣugbọn kì í ṣe ní ibojì àwọn ọba. +Baba wọn fún wọn ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn: fadaka, wúrà ati àwọn nǹkan olówó iyebíye, pẹlu àwọn ìlú olódi ní Juda. Ṣugbọn Jehoramu ni ó fi ìjọba lé lọ́wọ́, nítorí pé òun ni àkọ́bí rẹ̀. +Nígbà tí ó jọba tán, tí ó sì ti fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, ó fi idà pa gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ati díẹ̀ ninu àwọn olóyè ní Israẹli. +Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún mejilelọgbọn nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹjọ ní Jerusalẹmu. +Ó tẹ̀ sí ọ̀nà burúkú tí àwọn ọba Israẹli rìn, ó ṣe bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí pé ọmọ Ahabu ni iyawo rẹ̀. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. +Sibẹsibẹ OLUWA kò pa ìdílé Dafidi run nítorí majẹmu tí ó ti bá Dafidi dá, ati ìlérí tí ó ti ṣe pé ọmọ rẹ̀ ni yóo máa wà lórí oyè títí lae. +Ní àkókò ìjọba Jehoramu ni Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì yan ọba fún ara wọn. +Nítorí náà Jehoramu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ lọ gbógun tì wọ́n. Ní òru, Jehoramu ati ogun rẹ̀ dìde, wọ́n fọ́ ogun Edomu tí ó yí wọn ká tàwọn ti kẹ̀kẹ́ ogun wọn, ati àwọn tí ń wà wọ́n. +Jehoramu, Ọba Juda. +Àwọn ọmọ ogun Arabia tí wọn ń jà káàkiri pa gbogbo àwọn ọmọ Jehoramu, ọba Juda, àfi Ahasaya, àbíkẹ́yìn rẹ̀. Nítorí náà àwọn ará Jerusalẹmu bá fi Ahasaya jọba lẹ́yìn Jehoramu. +Nígbà tí Atalaya, ìyá Ahasaya rí i pé ọmọ òun ti kú, ó bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo ìran ọba ní Juda. +Ṣugbọn Jehoṣeba, ọmọbinrin Jehoramu ọba, tí ó jẹ́ iyawo Jehoiada alufaa, gbé Joaṣi ọmọ Ahasaya sá kúrò láàrin àwọn ọmọ ọba tí wọ́n fẹ́ pa, nítorí pé àbúrò rẹ̀ ni Joaṣi yìí. Ó bá fi òun ati olùtọ́jú rẹ̀ pamọ́ sinu yàrá kan. Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣeba ṣe gbé ọmọ náà pamọ́ fún Atalaya, tí kò fi rí i pa. +Joaṣi wà pẹlu wọn níbi tí wọ́n gbé e pamọ́ sí ninu ilé OLUWA fún ọdún mẹfa tí Atalaya fi jọba ní ilẹ̀ náà. +Ahasaya jẹ́ ẹni ọdún mejilelogoji, nígbà tí ó jọba; ó sì wà lórí oyè fún ọdún kan ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Atalaya, ọmọ ọmọ Omiri. +Ìwà burúkú ni òun náà ń hù bíi ti Ahabu, nítorí pé ìyá rẹ̀ ní ń darí rẹ̀ sí ọ̀nà ibi. +Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí pé lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, àwọn ará ilé Ahabu ni olùdámọ̀ràn rẹ̀, àwọn ni wọ́n fa ìṣubú rẹ̀. +Ìmọ̀ràn wọn ni ó tẹ̀lé tí ó fi pa ogun tirẹ̀ pọ̀ mọ́ ti Joramu, ọba Israẹli, láti bá Hasaeli ọba Siria jagun ní Ramoti Gileadi. Àwọn ará Siria sì ṣá Joramu lọ́gbẹ́ lójú ogun náà, +ó bá pada lọ sí ìlú Jesireeli láti wo ọgbẹ́ tí wọ́n ṣá a lójú ogun ní Rama nígbà tí ó ń bá Hasaeli ọba Siria jagun. Ahasaya, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò ní Jesireeli nítorí ara rẹ̀ tí kò yá. +Ọlọrun ti pinnu pé ìparun óo bá Ahasaya nígbà tí ó bá lọ bẹ Joramu wò. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, òun pẹlu Joramu lọ pàdé Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí OLUWA ti yàn pé òun ni yóo pa ìdílé Ahabu run. +Nígbà tí Jehu dé láti pa ilé Ahabu run bí Ọlọrun ti fún un láṣẹ, ó pàdé àwọn ìjòyè Juda ati ọmọ arakunrin Ahasaya tí ó bá Ahasaya wá, ó bá pa wọ́n. +Ó wá Ahasaya káàkiri títí; ní Samaria níbi tí ó sá pamọ́ sí ni wọ́n ti rí i mú, wọ́n bá mú un tọ Jehu wá, ó sì pa á. Wọ́n sin òkú rẹ̀, nítorí wọ́n ní, “Ọmọ ọmọ Jehoṣafati, ẹni tí ó fi tọkàntọkàn gbọ́ ti OLUWA ni.”Ní àkókò yìí, kò sí ẹnikẹ́ni ninu ìdílé Ahasaya tí ó lágbára tó láti jọba ilẹ̀ Juda. +Ahasaya Ọba Juda. +Ní ọdún keje Jehoiada alufaa mọ́kàn gírí, ó lọ bá àwọn marun-un ninu àwọn balogun dá majẹmu. Àwọn ni: Asaraya, ọmọ Jerohamu, Iṣimaeli ọmọ Jehohanani, Asaraya ọmọ Obedi, Maaseaya ọmọ Adaya ati Eliṣafati ọmọ Sikiri. +Ó ní kí àwọn eniyan náà dúró, kí wọn máa ṣọ́ ọba, olukuluku pẹlu ohun ìjà lọ́wọ́. Wọ́n tò láti ìhà gúsù ilé náà títí dé ìhà àríwá, ati ní àyíká pẹpẹ ati ti ilé náà. +Jehoiada bá mú Joaṣi jáde, ó gbé adé lé e lórí, ó fún un ní ìwé òfin. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fi Joaṣi jọba, Jehoiada alufaa ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì fi àmì òróró yàn án lọ́ba. Gbogbo eniyan hó pé, “Kí ọba pẹ́.” +Nígbà tí Atalaya gbọ́ híhó àwọn eniyan, ati bí wọ́n ti ń sá kiri tí wọ́n sì ń yin ọba, ó lọ sí ilé OLUWA níbi tí àwọn eniyan péjọ sí, +ó rí i tí ọba náà dúró lẹ́bàá òpó lẹ́nu ọ̀nà, àwọn ọ̀gágun ati àwọn tí wọn ń fọn fèrè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo eniyan ń hó ìhó ayọ̀, wọ́n ń fọn fèrè, àwọn tí ń lo ohun èlò orin ń fi wọ́n kọrin, àwọn eniyan sì ń gberin. Nígbà tí Atalaya rí nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ẹ̀rù bà á, ó sì kígbe lóhùn rara pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí! Ọ̀tẹ̀ nìyí!” +Jehoiada bá rán àwọn ọ̀gágun ọmọ ogun ọgọrun-un pé, “Ẹ fà á síta láàrin àwọn ọmọ ogun, ẹni tí ó bá tẹ̀lé e, ẹ pa á.” Nítorí àwọn alufaa ní kí wọ́n má pa á ninu tẹmpili OLUWA. +Wọ́n bá mú un lọ sí ẹnu ọ̀nà Ẹṣin, ní ààfin, wọ́n sì pa á sibẹ. +Jehoiada bá àwọn eniyan náà dá majẹmu pẹlu ọba, pé ti OLUWA ni àwọn yóo máa ṣe. +Lẹ́yìn náà, gbogbo wọn lọ sí ilé oriṣa Baali, wọ́n wó o palẹ̀, wọ́n wó pẹpẹ ati àwọn ère túútúú, wọ́n sì pa Matani, tí ó jẹ́ alufaa Baali, níwájú pẹpẹ. +Jehoiada yan àwọn aṣọ́nà fún ilé OLUWA, lábẹ́ àkóso àwọn alufaa, ọmọ Lefi, ati àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi ti ṣètò láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin Mose, pẹlu àjọyọ̀ ati orin, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣètò. +Ó fi àwọn aṣọ́nà sí ẹnu àwọn ọ̀nà ilé OLUWA kí ẹnikẹ́ni tí kò bá mọ́ má baà wọlé. +Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda, wọ́n lọ kó àwọn Lefi ati àwọn baálé baálé gbogbo ní Israẹli wá sí Jerusalẹmu. +Òun pẹlu àwọn balogun, àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn, àwọn gomina, ati gbogbo eniyan ilẹ̀ náà mú ọba láti ilé OLUWA, wọ́n gba ẹnu ọ̀nà òkè wá sí ààfin, wọ́n sì fi í jókòó lórí ìtẹ́. +Inú gbogbo àwọn eniyan dùn, ìlú sì rọ̀ wọ̀ọ̀, nítorí pé wọ́n ti pa Atalaya. +Gbogbo wọn pàdé ninu ilé Ọlọrun, wọ́n sì bá ọba dá majẹmu níbẹ̀. Jehoiada wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó! Ọmọ ọba nìyí, ó tó àkókò láti fi jọba nisinsinyii, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí OLUWA ṣe pé ìran Dafidi ni yóo máa jọba. +Ohun tí ẹ óo ṣe nìyí: nígbà tí àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi bá kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi, ìdámẹ́ta ninu wọn yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, +ìdámẹ́ta yóo wà ní ààfin ọba, ìdámẹ́ta tó kù yóo máa ṣọ́ Ẹnubodè Ìpìlẹ̀; gbogbo àwọn eniyan yóo sì péjọ sí gbọ̀ngàn ilé OLUWA. +Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọnú ilé OLUWA, àfi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́. Àwọn lè wọlé nítorí pé wọ́n mọ́. Ṣugbọn àwọn eniyan tí ó kù gbọdọ̀ pa àṣẹ OLUWA mọ́. +Àwọn ọmọ Lefi yóo yí ọba ká láti ṣọ́ ọ, olukuluku yóo mú ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n gbọdọ̀ wà pẹlu ọba níbikíbi tí ó bá ń lọ. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ wọnú ilé Ọlọrun, pípa ni kí ẹ pa á.” +Àwọn ọmọ Lefi ati gbogbo ọmọ Juda ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada alufaa ti pàṣẹ fún wọn. Olukuluku kó àwọn eniyan rẹ̀ tí wọ́n ṣíwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi wá, wọ́n dúró pẹlu àwọn tí wọ́n fẹ́ gba ipò wọn, nítorí Jehoiada alufaa kò jẹ́ kí wọ́n túká. +Jehoiada fún àwọn ọ̀gágun ní ọ̀kọ̀ ati apata Dafidi tí wọ́n ti kó pamọ́ sinu ilé Ọlọrun. +Wọ́n Dìtẹ̀ Mọ́ Atalaya. +Ọmọ ọdún meje ni Joaṣi nígbà tí ó gorí oyè, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ogoji ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sibaya, ará Beeriṣeba. +Gbogbo àwọn ìjòyè ati gbogbo eniyan fi tayọ̀tayọ̀ mú owó orí wọn wá, wọ́n ń sọ ọ́ sinu àpótí náà títí tí ó fi kún. +Nígbà tí àwọn Lefi bá gbé àpótí náà wá fún àwọn òṣìṣẹ́ ọba, tí wọ́n sì rí i pé owó pọ̀ ninu rẹ̀, akọ̀wé ọba ati aṣojú olórí alufaa yóo da owó kúrò ninu àpótí, wọn yóo sì gbé e pada sí ààyè rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ní ojoojumọ, wọ́n sì rí ọpọlọpọ owó kó jọ. +Ọba ati Jehoiada gbé owó náà fún àwọn tí wọn ń ṣe àkóso iṣẹ́ ilé OLUWA, wọ́n gba àwọn ọ̀mọ̀lé, àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn alágbẹ̀dẹ irin ati ti bàbà, láti tún ilé OLUWA ṣe. +Gbogbo àwọn tí wọ́n kópa ninu iṣẹ́ náà fi tagbára tagbára ṣe é. Iṣẹ́ náà tẹ̀síwájú títí tí wọ́n fi tún ilé OLUWA náà ṣe tán, tí ó sì rí bíi ti iṣaaju tí ó sì tún lágbára sí i. +Nígbà tí wọ́n tún ilé OLUWA náà ṣe tán, wọ́n kó owó tí ó kù pada sọ́dọ̀ ọba ati Jehoiada. Wọ́n fi owó náà ṣe àwọn ohun èlò fún ìsìn ati ẹbọ sísun ní ilé OLUWA, ati àwo fún turari ati ohun èlò wúrà ati fadaka.Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé OLUWA lojoojumọ, ní gbogbo àkókò Jehoiada. +Nígbà tí Jehoiada dàgbà tí ó di arúgbó, ó kú nígbà tí ó pé ẹni aadoje (130) ọdún. +Wọ́n sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi nítorí iṣẹ́ rere tí ó ṣe ní Israẹli fún Ọlọrun ati ní ilé mímọ́ rẹ̀. +Ṣugbọn nígbà tí Jehoiada kú, àwọn ìjòyè ní Juda wá kí ọba, wọ́n sì júbà rẹ̀, ó sì gba ìmọ̀ràn wọn. +Wọ́n kọ ilé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì ń sin oriṣa Aṣera ati àwọn ère mìíràn. Nítorí ìwà burúkú yìí, inú bí OLUWA sí Juda ati Jerusalẹmu. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA rán àwọn wolii sí wọn láti darí wọn pada sọ́dọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ fún wọn, wọ́n kọ etí dídi sí àwọn wolii. +Joaṣi ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé Jehoiada alufaa. +Nígbà tí ó yá, Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Sakaraya, ọmọ Jehoiada alufaa, ó bá dìde dúró láàrin àwọn eniyan, ó ní, “Ọlọrun ń bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi tàpá sí òfin òun OLUWA; ṣé ẹ kò fẹ́ kí ó dára fun yín ni? Nítorí pé, ẹ ti kọ OLUWA sílẹ̀, òun náà sì ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ” +Ṣugbọn wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn. Lẹ́yìn náà, ọba pàṣẹ pé kí wọn sọ ọ́ lókùúta pa ninu gbọ̀ngàn ilé OLUWA. +Joaṣi ọba kò ranti oore tí Jehoiada, baba Sakaraya ṣe fún un, ṣugbọn ó pa ọmọ rẹ̀. Nígbà tí ó sì ń kú lọ, ó ní, “Kí OLUWA wo ohun tí o ṣe yìí, kí ó sì gbẹ̀san.” +Bí ọdún náà ti ń dópin lọ, àwọn ọmọ ogun Siria gbógun ti Joaṣi. Nígbà tí wọ́n dé Juda ati Jerusalẹmu, wọ́n pa gbogbo àwọn ìjòyè wọn, wọ́n sì kó gbogbo ìkógun wọn ranṣẹ sí Damasku. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n wá, sibẹsibẹ OLUWA fi ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ ogun Juda lé wọn lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA Ọlọrun baba wọn sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìdájọ́ Joaṣi ọba. +Ọba fara gbọgbẹ́ ninu ogun náà, nígbà tí àwọn ogun Siria sì lọ tán, àwọn balogun rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn nítorí pé ó pa ọm��� Jehoiada alufaa, wọ́n sì pa á lórí ibùsùn rẹ̀. Wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, ṣugbọn kì í ṣe inú ibojì àwọn ọba. +Àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọba ni Sabadi, ọmọ Ṣimeati ará Amoni, ati Jehosabadi ọmọ Ṣimiriti ará Moabu. +Ìtàn àwọn ọmọ rẹ̀, ati ọpọlọpọ àsọtẹ́lẹ̀ tí a sọ nípa rẹ̀, ati bí ó ti tún ilé Ọlọrun ṣe wà, tí a kọ ọ́ sinu ìwé Ìtàn Àwọn Ọba. Amasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Jehoiada fẹ́ iyawo meji fún un, wọ́n sì bímọ fún un lọkunrin ati lobinrin. +Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Joaṣi pinnu láti tún ilé OLUWA ṣe. +Ó pe gbogbo àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Juda, kí ẹ máa gba owó lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli láti máa fi tún ilé OLUWA Ọlọrun yín ṣe ní ọdọọdún. Ẹ mójútó iṣẹ́ náà kí ẹ sì ṣe é kíákíá.” Ṣugbọn àwọn alufaa kò tètè lọ. +Nítorí náà, ọba ranṣẹ pe Jehoiada tí ó jẹ́ olórí wọn, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Lefi lọ máa gba owó fún àgọ́ ẹ̀rí lọ́wọ́ àwọn eniyan Juda ati Jerusalẹmu bí Mose, iranṣẹ OLUWA, ti pa á láṣẹ?” +(Nítorí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Atalaya, obinrin burúkú n nì, ti fọ́ ilé Ọlọrun, wọ́n sì ti kó gbogbo ohun èlò mímọ́ ibẹ̀, wọ́n ti lò ó fún oriṣa Baali.) +Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe àpótí kan tí àwọn eniyan yóo máa sọ owó sí, kí wọ́n sì gbé e sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA. +Wọ́n kéde káàkiri Jerusalẹmu ati Juda pé kí wọ́n máa mú owó orí wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí Mose iranṣẹ Ọlọrun ti pàṣẹ fún Israẹli ninu aṣálẹ̀. +Joaṣi, Ọba Juda. +Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Amasaya nígbà tí ó jọba; ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn ní Jerusalẹmu. Ìyá rẹ̀ ni Jehoadini ará Jerusalẹmu. +Nítorí náà Amasaya dá àwọn ọmọ ogun Efuraimu tí ó gbà pada sílé wọn. Nítorí náà, inú bí wọn gan-an sí Juda, wọ́n sì pada sílé pẹlu ìrúnú. +Ṣugbọn Amasaya fi ìgboyà kó ogun rẹ̀ lọ sí Àfonífojì Iyọ̀, ó sì pa ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ọmọ ogun Seiri. +Wọ́n mú ẹgbaarun (10,000) mìíràn láàyè, wọ́n kó wọn lọ sí góńgó orí òkè kan, wọ́n jù wọ́n sí ìsàlẹ̀, gbogbo wọn sì ṣègbé. +Àwọn ọmọ ogun Israẹli tí Amasaya dá pada, tí kò jẹ́ kí wọ́n tẹ̀lé òun lọ sógun bá lọ, wọ́n kọlu àwọn ìlú Juda láti Samaria títí dé Beti Horoni. Wọ́n pa ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun. +Amasaya kó oriṣa àwọn ará Edomu tí ó ṣẹgun wá sílé. Ó kó wọn kalẹ̀, ó ń bọ wọ́n, ó sì ń rúbọ sí wọn. +Inú bí OLUWA sí Amasaya gan-an, ó sì rán wolii kan sí i kí ó sọ fún un pé, “Kí ló dé tí o fi ń bọ àwọn oriṣa tí kò lè gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ?” +Bí wolii yìí ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dá a lóhùn pé, “Panumọ́, ṣé wọ́n fi ọ́ ṣe olùdámọ̀ràn ọba ni? Àbí o fẹ́ kú ni.”Wolii náà bá dákẹ́, ṣugbọn, kí ó tó dákẹ́ ó ní, “Mo mọ̀ pé Ọlọrun ti pinnu láti pa ọ́ run fún ohun tí o ṣe yìí, ati pé, o kò tún fetí sí ìmọ̀ràn mi.” +Lẹ́yìn tí Amasaya, ọba Juda, ṣe àpérò pẹlu àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, ó ranṣẹ sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu, ọba Israẹli pé, “Wá, jẹ́ kí á kojú ara wa.” +Jehoaṣi ọba Israẹli ranṣẹ sí ọba Juda pé, “Ní àkókò kan, ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n kan ní Lẹbanoni ranṣẹ sí igi kedari ní Lẹbanoni pé, ‘Mo fẹ́ fẹ́ ọmọbinrin rẹ fún ọmọkunrin mi.’ Ẹranko ìgbẹ́ kan ń kọjá lọ, ó sì tẹ ẹ̀gún náà mọ́lẹ̀. +O bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé o ti ṣẹgun àwọn ará Edomu, ṣugbọn, mo gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn pé kí o dúró jẹ́ẹ́ sí ilé rẹ. Kí ló dé tí ò ń fi ọwọ́ ara rẹ fa ìjàngbọ̀n tí ó lè fa ìṣubú ìwọ ati àwọn eniyan rẹ?” +Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ṣugbọn kò fi tọkàntọkàn sìn ín. +Ṣugbọn Amasaya kọ̀, kò gbọ́, nítorí pé Ọlọrun ni ó mú kí ọkàn rẹ̀ le, kí Ọlọrun lè fi Juda lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Edomu. +Nítorí náà, Jehoaṣi, ọba Israẹli, gòkè lọ, òun ati Amasaya ọba Juda sì kojú ara wọn lójú ogun ní Beti Ṣemeṣi ní ilẹ̀ Juda. +Àwọn ará Israẹli ṣẹgun àwọn ará Juda, olukuluku sì fọ́nká lọ sí ilé rẹ̀. +Jehoaṣi, ọba Israẹli mú Amasaya, ọba Juda, ọmọ Joaṣi, ọmọ Ahasaya, ní ojú ogun, ní Beti Ṣemeṣi; ó sì mú un wá sí Jerusalẹmu. Ó wó odi Jerusalẹmu palẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Kọ̀rọ̀. Gígùn ibi tí à ń wí yìí jẹ́ irinwo igbọnwọ (200 mita.) +Ó kó gbogbo wúrà, fadaka ati àwọn ohun èlò tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú Obedi Edomu ní ilé Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ààfin ọba, ó kó gbogbo ìṣúra tí ó wà níbẹ̀ ati àwọn eniyan, ó sì pada sí Samaria. +Amasaya, ọmọ Joaṣi, ọba Juda gbé ọdún mẹẹdogun lẹ́yìn ikú Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, ọba Israẹli. +Àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yòókù tí Amasaya ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu ìwé àwọn ọba Juda ati Israẹli. +Láti ìgbà tí Amasaya ti pada lẹ́yìn OLUWA ni àwọn eniyan ti dìtẹ̀ mọ́ ọn ní Jerusalẹmu, nítorí náà, ó sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n lépa rẹ̀ lọ sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á níbẹ̀. +Wọ́n fi ẹṣin gbé òkú rẹ̀ wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sí ìlú Dafidi ní ibojì àwọn baba rẹ̀. +Lẹ́yìn ìgbà tí ìjọba rẹ̀ ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, ó pa gbogbo àwọn tí wọ́n pa baba rẹ̀. +Ṣugbọn kò pa àwọn ọmọ wọn, gẹ́gẹ́ bí ìwé òfin Mose ti wí, níbi tí OLUWA ti pàṣẹ, pé, “A kò gbọdọ̀ pa baba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ, tabi kí á pa ọmọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba; olukuluku ni yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.” +Amasaya pe àwọn eniyan Juda ati Bẹnjamini jọ, ó pín wọn sábẹ́ àwọn ọ̀gágun ní ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ ni gbogbo àwọn tí ó kó jọ. Gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) akọni ọkunrin tí wọ́n tó lọ sójú ogun, tí wọ́n sì lè lo ọ̀kọ̀ ati apata. +Ó tún fi ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti fadaka lọ bẹ ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) akọni lọ́wẹ̀ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli. +Ṣugbọn wolii Ọlọrun kan lọ bá Amasaya, ó sọ fún un pé, “Kabiyesi, má jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Israẹli bá ọ lọ, nítorí OLUWA kò ní wà pẹlu Israẹli ati àwọn ará Efuraimu wọnyi. +Ṣugbọn bí o bá wá rò pé àwọn wọnyi ni yóo jẹ́ kí ogun rẹ lágbára, OLUWA yóo bì ọ́ ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá rẹ. Nítorí Ọlọrun lágbára láti ranni lọ́wọ́ ati láti bini ṣubú.” +Amasaya bèèrè lọ́wọ́ wolii náà pé, “Kí ni kí á ṣe nípa ọgọrun-un talẹnti tí mo ti fún àwọn ọmọ ogun Israẹli?”Ó dáhùn pé, “OLUWA lè fún ọ ní ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.” +Amasaya, Ọba Juda. +Gbogbo àwọn ará Juda fi Usaya, ọmọ ọdún mẹrindinlogun jọba lẹ́yìn ikú Amasaya baba rẹ̀. +Ó tún kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ sinu aṣálẹ̀, ó gbẹ́ ọpọlọpọ kànga, nítorí pé ó ní ọpọlọpọ agbo ẹran ọ̀sìn ní àwọn ẹsẹ̀ òkè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn ń dá oko fún un ati àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu àjàrà, lórí òkè ati lórí àwọn ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn iṣẹ́ àgbẹ̀. +Usaya ní ọpọlọpọ ọmọ ogun, tí wọ́n tó ogun lọ, ó pín wọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí ètò tí Jeieli akọ̀wé, ati Maaseaya, ọ̀gágun ṣe, lábẹ́ àkóso Hananaya, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun ọba. +Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé, tí wọ́n sì jẹ́ akọni ọkunrin jẹ́ ẹgbẹtala (2,600). +Àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà lábẹ́ wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdogun ó lé ẹẹdẹgbaarin ati ẹẹdẹgbaata (307,500), wọ́n lágbára láti jagun, ati láti bá ọba dojú kọ àwọn ọ̀tá rẹ̀. +Usaya ọba fún gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní apata, ọ̀kọ̀, àṣíborí, ẹ̀wù ihamọra, ọfà, ati òkúta fún kànnàkànnà wọn. +Ó ní àwọn ẹ̀rọ tí àwọn alágbẹ̀dẹ ṣe sórí àwọn ilé ìṣọ́ ati àwọn igun odi ní Jerusalẹmu láti máa tafà ati láti máa sọ àwọn òkúta ńláńlá. Òkìkí rẹ̀ sì kàn káàkiri nítorí pé Ọlọrun ràn án lọ́wọ́ ní ọ̀nà ìyanu títí ó fi di alágbára. +Ṣugbọn nígbà tí Usaya di alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ tì í ṣubú. Ó ṣe aiṣootọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ó wọ inú tẹmpili OLUWA, ó lọ sun turari lórí pẹpẹ turari. +Ṣugbọn Asaraya, alufaa, wọlé lọ bá a pẹlu àwọn ọgọrin alufaa tí wọ́n jẹ́ akọni. +Wọ́n dojú kọ ọ́, wọ́n ní, “Usaya, kò tọ́ fún ọ láti sun turari sí OLUWA; iṣẹ́ àwọn alufaa tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni ni, àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ láti máa sun turari. Jáde kúrò ninu ibi mímọ́! Nítorí o ti ṣe ohun tí kò tọ́, kò sì buyì kún ọ lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun rẹ.” +Inú bí Usaya nítorí pé àwo turari ti wà lọ́wọ́ rẹ̀ tí ó fẹ́ fi sun turari. Níbi tí ó ti ń bínú sí àwọn alufaa, àrùn ẹ̀tẹ̀ yọ níwájú rẹ̀, lójú àwọn alufaa ninu ilé OLUWA. +Ó tún Eloti kọ́, ó gbà á pada fún Juda lẹ́yìn ikú Amasaya, baba rẹ̀. +Nígbà tí Asaraya, olórí alufaa ati àwọn alufaa rí i tí ẹ̀tẹ̀ yọ níwájú rẹ̀, wọ́n yára tì í jáde. Ìkánjú ni òun pàápàá tilẹ̀ bá jáde, nítorí pé OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà. +Usaya ọba di adẹ́tẹ̀ títí ọjọ́ ikú rẹ̀. Ọ̀tọ̀ ni wọ́n kọ́ ilé fún un tí ó ń dá gbé; nítorí wọ́n yọ ọ́ kúrò ninu ilé OLUWA. Jotamu ọmọ rẹ̀ di alákòóso ìjọba, ó sì ń darí àwọn ará ìlú. +Àwọn nǹkan yòókù tí Usaya ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu àkọsílẹ̀ wolii Aisaya, ọmọ Amosi. +Nígbà tí Usaya kú, wọ́n sin ín sí itẹ́ àwọn ọba, wọn kò sin ín sinu ibojì àwọn ọba, nítorí wọ́n ní, “Adẹ́tẹ̀ ni.” Jotamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ọmọ ọdún mẹrindinlogun ni Usaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mejilelaadọta. Jekolaya, ará Jerusalẹmu ni ìyá rẹ̀. +Ó ṣe nǹkan tí ó tọ́ níwájú OLUWA, bí Amasaya baba rẹ̀. +Ó sin Ọlọrun nígbà ayé Sakaraya, nítorí pé Sakaraya ń kọ́ ọ ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. Ní gbogbo àkókò tí ó fi ń sin Ọlọrun, Ọlọrun bukun un. +Ó gbógun ti àwọn ará Filistia, ó sì wó odi Gati, ati ti Jabine ati ti Aṣidodu lulẹ̀. Ó kọ́ àwọn ìlú olódi ní agbègbè Aṣidodu ati ní ibòmíràn ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia. +Ọlọrun ràn án lọ́wọ́, ó ṣẹgun àwọn ará Filistia ati àwọn ará Arabia tí wọ́n ń gbé Guribaali ati àwọn ará Meuni. +Àwọn ará Amoni ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún Usaya, òkìkí rẹ̀ kàn káàkiri títí dé agbègbè ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé ó di alágbára gan-an. +Usaya tún kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi Ẹnubodè tí ó wà ní igun odi, ati sí ibi Ẹnubodè àfonífojì, ati níbi Ìṣẹ́po Odi. Ó sì mọ odi sí wọn. +Usaya, Ọba Juda. +Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Jotamu nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹrindinlogun. Jeruṣa, ọmọ Sadoku ni ìyá rẹ̀. +Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA, gẹ́gẹ́ bíi Usaya, baba rẹ̀; àfi pé òun kò lọ sun turari ninu tẹmpili OLUWA. Ṣugbọn àwọn eniyan ń bá ìwà burúkú wọn lọ. +Ó kọ́ ẹnu ọ̀nà òkè ilé OLUWA, ó sì tún ògiri Ofeli mọ. +Ó kọ́ àwọn ìlú ní agbègbè olókè Juda ó sì kọ́ ibi ààbò ati ilé-ìṣọ́ ninu igbó lára òkè. +Ó bá ọba àwọn ará Amoni jà, ó sì ṣẹgun wọn. Ní ọdún tí ó ṣẹgun wọn, wọ́n fún un ní ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n kori alikama ati ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n kori ọkà baali. Iye kan náà ni wọ́n fún un ní ọdún keji ati ọdún kẹta. +Jotamu di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ̀. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Jotamu ṣe ati àwọn ogun tí ó jà, ati àwọn nǹkan mìíràn tí ó tún ṣe ni a kọ sinu ìwé àwọn ọba Israẹli ati ti Juda. +Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. +Nígbà tí Jotamu kú, wọ́n sin ín ní ìlú Dafidi, Ahasi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Jotamu, Ọba Juda. +Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. Kò sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA bíi Dafidi baba ńlá rẹ̀. +Ẹ tún wá fẹ́ kó tọkunrin tobinrin Juda ati Jerusalẹmu lẹ́rú. Ṣé ẹ̀yin alára náà kò ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín? +Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ dá àwọn arakunrin yín tí ẹ ti kó lẹ́rú pada, nítorí ibinu OLUWA wà lórí yín.” +Nígbà náà ni àwọn ìjòyè kan lára àwọn ará Efuraimu: Asaraya, ọmọ Johanani, Berekaya, ọmọ Meṣilemoti, Jehisikaya, ọmọ Ṣalumu ati Amasa, ọmọ Hadilai dìde, wọ́n tako àwọn tí ń ti ojú ogun bọ̀, wọ́n sọ fún wọn pé, +“Ẹ kò gbọdọ̀ kó àwọn ìgbèkùn wọnyi wọ ibí wá, kí ẹ tún wá dákún ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹ̀bi tí ó wà lọ́rùn wa tẹ́lẹ̀. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ tẹ́lẹ̀, ọwọ́ ibinu OLUWA sì ti wà lára Israẹli.” +Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun náà dá àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú ati ẹrù tí wọn ń kó bọ̀ sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè ati gbogbo ìjọ eniyan Israẹli. +Àwọn kan tí wọ́n yàn bá dìde, wọ́n kó àwọn tí àwọn ọmọ ogun kó lẹ́rú ati ẹrù wọn, wọ́n wọ àwọn tí wọ́n wà ní ìhòòhò láṣọ; wọ́n fún wọn ní bàtà, wọ́n pèsè oúnjẹ ati nǹkan mímu fún wọn, wọ́n sì fi òróró sí ọgbẹ́ wọn. Wọ́n gbé gbogbo àwọn tí àárẹ̀ ti mú gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin wọn ní Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n pada lọ sí Samaria. +Ní àkókò yìí, Ahasi ranṣẹ lọ bẹ ọba Asiria lọ́wẹ̀, +nítorí pé àwọn ará Edomu tún pada wá gbógun ti Juda; wọ́n ṣẹgun wọn, wọ́n sì kó àwọn kan ninu wọn lẹ́rú lọ. +Àwọn ará Filistia ti gbógun ti àwọn ìlú tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati ní agbègbè Nẹgẹbu, ní Juda. Wọ́n jagun gba Beti Ṣemeṣi, Aijaloni, ati Gederotu, wọ́n sì gba Soko, Timna, ati Gimso pẹlu àwọn ìletò ìgbèríko wọn, wọ́n bá ń gbé ibẹ̀. +OLUWA rẹ Juda sílẹ̀ nítorí Ahasi, ọba Juda, nítorí pé ó hùwà ìríra ní Juda, ó sì ṣe aiṣootọ sí OLUWA. +Ṣugbọn ó ṣe bí àwọn ọba Israẹli, ó tilẹ̀ yá ère fún oriṣa Baali. +Nítorí náà Tigilati Pileseri, ọba Asiria gbógun ti Ahasi, ó sì fìyà jẹ ẹ́, dípò kí ó ràn án lọ́wọ́. +Ahasi kó ohun ìṣúra inú ilé OLUWA, ati ti ààfin, ati ti inú ilé àwọn ìjòyè, ó fi san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Asiria, sibẹsibẹ ọba Asiria kò ràn án lọ́wọ́. +Ní àkókò ìyọnu Ahasi ọba, ó túbọ̀ ṣe alaiṣootọ sí OLUWA ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. +Ó rúbọ sí àwọn oriṣa àwọn ará Damasku tí wọ́n ṣẹgun rẹ̀, nítorí ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Àwọn oriṣa àwọn ọba Siria ràn wọ́n lọ́wọ́, n óo rúbọ sí wọn kí wọ́n lè ran èmi náà lọ́wọ́.” Ṣugbọn àwọn oriṣa ọ̀hún ni wọ́n fa ìparun bá òun ati orílẹ̀-èdè rẹ̀. +Gbogbo ohun èlò ilé Ọlọrun ni Ahasi gé wẹ́wẹ́, ó sì ti ìlẹ̀kùn ibẹ̀; ó wá tẹ́ pẹpẹ oriṣa káàkiri Jerusalẹmu. +Ó ṣe ibi ìrúbọ káàkiri àwọn ìlú Juda níbi tí yóo ti máa sun turari sí àwọn oriṣa. Nípa bẹ́ẹ̀, ó mú OLUWA Ọlọrun àwọn baba rẹ̀ bínú. +Àkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasi ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, wà ninu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati ti Israẹli. +Nígbà tí Ahasi ọba kú, wọ́n sin ín sí Jerusalẹmu, wọn kò sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba. Hesekaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ó ń sun turari ní àfonífojì àwọn ọmọ Hinomu, ó sì ń fi àwọn ọmọkunrin rẹ̀ rú ẹbọ sísun, gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú Israẹli ń hù. +Ó rúbọ, ó sun turari ní àwọn ibi ìrúbọ, ati lórí òkè káàkiri ati lábẹ́ gbogbo igi tútù. +Nítorí náà OLUWA Ọlọrun rẹ̀ fi í lé ọba Siria lọ́wọ́. Ọba Siria ṣẹgun rẹ̀, ó sì kó àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́rú lọ sí Damasku. Ọlọrun tún fi lé ọba Israẹli lọ́wọ́, ó ṣẹgun rẹ̀, ó sì pa àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní ìpakúpa. +Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, Peka, ọmọ Remalaya, ọba Israẹli, pa ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) ninu àwọn ọmọ ogun Juda; tí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni. Ọlọrun jẹ́ kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀. +Sikiri, akikanju jagunjagun kan, ará Efuraimu pa Maaseaya, ọmọ ọba, ati Asirikamu, olórí ogun tí ń ṣọ́ ààfin ọba, ati Elikana, igbákejì ọba. +Àwọn tí ará ilẹ̀ Israẹli dè ní ìgbèkùn lọ ninu àwọn ará ilé Juda jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àtàwọn obinrin, àtàwọn ọmọkunrin, àtàwọn ọmọbinrin; wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun lọ sí Samaria. +Wolii OLUWA kan tí ń jẹ́ Odedi wà ní ìlú Samaria; ó lọ pàdé àwọn ọmọ ogun Israẹli nígbà tí wọ́n ń pada bọ̀. Ó wí fún wọn pé, “Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín bínú sí àwọn ará Juda ni ó fi jẹ́ kí ẹ ṣẹgun wọn, ṣugbọn ẹ pa wọ́n ní ìpakúpa tóbẹ́ẹ̀ tí Ọlọrun pàápàá ṣàkíyèsí rẹ̀. +Ahasi, Ọba Juda. +Hesekaya jọba ní Juda nígbà tí ó di ẹni ọdún mẹẹdọgbọn; ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Abija, ọmọ Sakaraya. +“Nisinsinyii, mo ti pinnu láti bá OLUWA Ọlọrun Israẹli dá majẹmu, kí ibinu gbígbóná rẹ̀ lè kúrò lórí wa. +Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má jáfara, nítorí pé OLUWA ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀, ati láti sìn ín; láti jẹ́ iranṣẹ rẹ̀ ati láti máa sun turari sí i.” +Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe ní tẹmpili nìwọ̀nyí: láti inú ìdílé Kohati: Mahati, ọmọ Amasai, ati Joẹli, ọmọ Asaraya; láti inú ìdílé Merari: Kiṣi, ọmọ Abidi ati Asaraya, ọmọ Jahaleleli; láti inú ìdílé Geriṣoni: Joa, ọmọ Sima ati Edẹni, ọmọ Joa. +Láti inú ìdílé Elisafani: Ṣimiri ati Jeueli; láti inú ìdílé Asafu: Sakaraya ati Matanaya, +láti inú ìdílé Hemani: Jeueli ati Ṣimei; láti inú ìdílé Jedutuni: Ṣemaaya ati Usieli. +Wọ́n bá kó àwọn arakunrin wọn jọ, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́. Wọ́n wọ ilé OLUWA láti tọ́jú rẹ̀ bí ọba ti pa á láṣẹ, gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA. +Àwọn alufaa wọ ibi mímọ́ lọ láti tọ́jú rẹ̀. Gbogbo ohun aláìmọ́ tí wọ́n rí ninu tẹmpili OLUWA ni wọ́n kó sí àgbàlá ilé náà. Àwọn ọmọ Lefi sì kó gbogbo wọn lọ dà sí odò Kidironi lẹ́yìn ìlú. +Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ya ara wọn sí mímọ́ ní ọjọ́ kinni oṣù kinni. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá sí yàrá àbáwọlé ilé OLUWA. Ọjọ́ mẹjọ ni wọ́n fi ya ilé OLUWA sí mímọ́, wọ́n parí ní ọjọ́ kẹrindinlogun oṣù náà. +Lẹ́yìn náà, wọ́n tọ Hesekaya ọba lọ, wọ́n sọ fún un pé, “A ti tọ́jú ilé OLUWA: ati pẹpẹ ẹbọ sísun, ati gbogbo ohun èlò rẹ̀, ati tabili àkàrà ìfihàn ati gbogbo ohun èlò rẹ̀. +Gbogbo àwọn ohun èlò tí Ahasi ọba ti patì nígbà tí ó ṣe aiṣododo ni a ti tọ́jú, tí a sì ti yà sí mímọ́. A ti kó gbogbo wọn siwaju pẹpẹ OLUWA.” +Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA, gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti ṣe. +Hesekaya ọba dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó kó gbogbo àwọn ìjòyè ìlú jọ, wọ́n bá lọ sinu ilé OLUWA. +Wọ́n fi akọ mààlúù meje, àgbò meje, ọ̀dọ́ aguntan meje ati òbúkọ meje rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba Hesekaya, ati ilé OLUWA ati ilé Juda. Ọba pàṣẹ pé kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni, fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ OLUWA. +Àwọn akọ mààlúù ni wọ́n kọ́kọ́ pa, àwọn alufaa gba ẹ̀jẹ̀ wọn, wọ́n dà á sára pẹpẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n pa àwọn àgbò, wọ́n sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sára pẹpẹ. +Lẹ́yìn náà wọ́n kó àwọn òbúkọ fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wá sọ́dọ̀ ọba ati ìjọ eniyan, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn lórí. +Àwọn alufaa pa àwọn òbúkọ náà, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn rúbọ lórí pẹpẹ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ọmọ Israẹli, nítorí ọba ti pàṣẹ pé wọ́n gbọdọ̀ rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo eniyan. +Ọba pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Lefi dúró ninu ilé OLUWA pẹlu ohun èlò orin bíi kimbali, hapu ati dùùrù, gẹ́gẹ́ bí i àṣẹ tí OLUWA pa, láti ẹnu Dafidi ati wolii Gadi tí í ṣe aríran ọba, ati wolii Natani. +Àwọn ọmọ Lefi dúró pẹlu ohun èlò orin Dafidi, àwọn alufaa sì dúró pẹlu fèrè. +Hesekaya pàṣẹ pé kí wọ́n rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ náà, àwọn akọrin bẹ̀rẹ̀ sí kọrin sí OLUWA pẹlu fèrè ati àwọn ohun èlò orin Dafidi, ọba Israẹli. +Ọba ati ìjọ eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí sin OLUWA, àwọn akọrin ń kọrin, àwọn afunfèrè ń fun fèrè títí tí ẹbọ sísun náà fi parí. +Nígbà tí wọ́n rú ẹbọ sísun tán, ọba ati ìjọ eniyan wólẹ̀, wọ́n sin Ọlọrun. +Ní oṣù kinni ọdún kinni ìjọba rẹ̀, ó ṣí àwọn ìlẹ̀kùn ilé OLUWA, ó sì tún wọn ṣe. +Ọba ati àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n kọ orin ìyìn Dafidi ati ti Asafu, aríran. Wọ́n fi ayọ̀ kọ orin ìyìn náà, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. +Hesekaya bá sọ fún wọn pé: “Nisinsinyii tí ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún OLUWA, ẹ wá, kí ẹ sì mú ọrẹ ati ẹbọ ọpẹ́ wá sí ilé OLUWA.” Ìjọ eniyan sì mú ọrẹ ati ẹbọ ọpẹ́ wá, àwọn tí wọ́n fẹ́ sì mú ẹbọ sísun wá. +Àwọn nǹkan tí wọn mú wá jẹ́ aadọrin akọ mààlúù, ọgọrun-un (100) àgbò, igba (200) ọ̀dọ́ aguntan, gbogbo rẹ̀ wà fún ẹbọ sísun sí OLUWA. +Àwọn ẹran tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ẹbọ jẹ́ ẹgbẹta (600) akọ mààlúù, ati ẹgbẹẹdogun (3,000) aguntan. +Àwọn alufaa kò pọ̀ tó láti pa gbogbo ẹran náà, nítorí náà, kí ó tó di pé àwọn alufaa mìíràn yóo ya ara wọn sí mímọ́, àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Lefi, ràn wọ́n lọ́wọ́ títí iṣẹ́ náà fi parí. Àwọn ọmọ Lefi ṣe olóòótọ́ ní yíya ara wọn sí mímọ́ ju àwọn alufaa lọ. +Yàtọ̀ sí ọpọlọpọ ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀rá rú ẹbọ alaafia ati ẹbọ ohun mímu fún ẹbọ sísun.Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ìsìn ninu ilé OLUWA ṣe tún bẹ̀rẹ̀. +Hesekaya ati ìjọ eniyan yọ̀ nítorí ohun tí Ọlọrun ṣe fún wọn, nítorí láìròtẹ́lẹ̀ ni gbogbo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀. +Ó kó àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi jọ sí gbàgede tí ó wà ní apá ìlà oòrùn ilé Ọlọrun. +Ó ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Lefi, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì ya ilé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba yín sí mímọ́ pẹlu. Ẹ kó gbogbo àwọn nǹkan ẹ̀gbin kúrò ninu ibi mímọ́, +nítorí àwọn baba wa ti ṣe aiṣododo, wọ́n sì ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, Ọlọrun wa. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọ́n gbójú kúrò lára ibùgbé rẹ̀, wọ́n sì kẹ̀yìn sí i. +Wọ́n ti ìlẹ̀kùn yàrá àbáwọlé tẹmpili, wọ́n pa fìtílà tí ó wà ní ibi mímọ́, wọn kò sun turari, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rú ẹbọ sísun ní ibi mímọ́ sí Ọlọrun Israẹli. +Nítorí náà ni OLUWA ṣe bínú sí Juda ati Jerusalẹmu, ohun tí Ọlọrun fi wọ́n ṣe sì dẹ́rùba gbogbo eniyan. Wọ́n di ẹni ẹ̀gàn ati ẹni àrípòṣé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i lónìí. +Ìdí nìyí tí àwọn baba wa fi ṣubú lójú ogun tí wọ́n sì kó àwọn ọmọ ati àwọn aya wa lẹ́rú. +Hesekaya, Ọba Juda. +Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ tẹmpili OLUWA ní Jerusalẹmu, níbi ìpakà Onani, ará Jebusi, lórí òkè Moraya, níbi tí OLUWA ti fi ara han Dafidi, baba rẹ̀; Dafidi ti tọ́jú ibẹ̀ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. +Ó fi igi gbẹ́ kerubu meji, ó yọ́ wúrà bò wọ́n, ó sì gbé wọn sí ibi mímọ́ jùlọ. +Gígùn gbogbo ìyẹ́ kerubu mejeeji jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ kerubu kinni keji jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ kerubu kinni nà kan ògiri ilé náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ìyẹ́ rẹ̀ keji tí òun náà jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), nà kan ìyẹ́ kerubu keji. +Ekinni ninu àwọn ìyẹ́ kerubu keji náà jẹ́ igbọnwọ marun-un, ó nà kan ògiri ilé náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji, ìyẹ́ rẹ̀ keji náà jẹ́ igbọnwọ marun-un, òun náà nà kan ìyẹ́ ti kerubu kinni. +Àwọn kerubu yìí dúró, wọ́n kọjú sí gbọ̀ngàn ilé náà; gígùn gbogbo ìyẹ́ wọn jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). +Ó fi aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, ti àlàárì ati aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe aṣọ ìbòjú fún ibi mímọ́ jùlọ, ó sì ya àwòrán kerubu sí i lára. +Ó ṣe òpó meji sí iwájú ilé náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ ga ní igbọnwọ marundinlogoji (mita 15). Ọpọ́n orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ga ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un (mita 2¼). +Ó ṣe àwọn nǹkankan bí ẹ̀wọ̀n, ó fi wọ́n sórí àwọn òpó náà. Ó sì ṣe ọgọrun-un (100) èso pomegiranate, ó so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà. +Ó gbé àwọn òpó náà kalẹ̀ níwájú tẹmpili, ọ̀kan ní ìhà àríwá, wọ́n ń pè é ní Jakini, ekeji ní ìhà gúsù, wọ́n ń pè é ní Boasi. +Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà ní ọjọ́ keji oṣù keji ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. +Ìpìlẹ̀ ilé Ọlọrun tí Solomoni fi lélẹ̀ gùn ní ọgọta igbọnwọ (mita 27), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). +Yàrá kan wà ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé tí ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó ga ní ọgọfa igbọnwọ (mita 54), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ déédé ìbú tẹmpili. +Ó yọ́ ojúlówó wúrà bo gbogbo inú rẹ̀. Ó fi igi sipirẹsi tẹ́ gbogbo inú gbọ̀ngàn rẹ̀. Ó sì yọ́ wúrà dáradára bò ó lórí, ó ya igi ọ̀pẹ ati ẹ̀wọ̀n, ó fi dárà sórí rẹ̀. +Ó fi òkúta olówó iyebíye ṣe iṣẹ́ ọnà sára ilé náà, wúrà tí ó rà wá láti ilẹ̀ Pafaimu ni ó lò. +Ó yọ́ wúrà bo gbogbo igi àjà ilé náà patapata, ati àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀, ògiri rẹ̀ ati àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀; ó sì fi àwòrán àwọn kerubu dárà sí ara àwọn ògiri. +Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ ṣe déédé ìbú tẹmpili náà, ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9). Ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó yọ́ ìwọ̀n ẹgbẹta (600) talẹnti ojúlówó wúrà, ó fi bo gbogbo inú rẹ̀. +Aadọta ìwọ̀n ṣekeli wúrà ni ó fi ṣe ìṣó, ó sì yọ́ wúrà bo gbogbo ara ògiri yàrá òkè. +Àwọn Òpó Idẹ Meji. +Hesekaya ranṣẹ sí gbogbo Juda ati Israẹli. Ó kọ̀wé sí Efuraimu ati Manase pẹlu, pé kí gbogbo wọ́n wá sí ilé OLUWA ní Jerusalẹmu láti wá ṣe Àjọ Ìrékọjá ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. +Àwọn oníṣẹ́ ọba lọ láti ìlú kan dé ekeji jákèjádò ilẹ̀ Efuraimu ati ti Manase, títí dé ilẹ̀ Sebuluni. Ṣugbọn àwọn eniyan fi wọ́n rẹ́rìn-ín, wọ́n sì fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà. +Àfi díẹ̀ ninu àwọn ará Aṣeri, Manase, ati Sebuluni ni wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n wá sí Jerusalẹmu. +Ọlọrun lọ́wọ́ sí ohun tí àwọn ará Juda ń ṣe, ó fi sí wọn ní ọkàn láti mú àṣẹ tí ọba ati àwọn olórí pa fún wọn ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA. +Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ ní Jerusalẹmu ní oṣù keji láti ṣe Àjọ Àìwúkàrà. +Wọ́n wó gbogbo pẹpẹ oriṣa ati àwọn pẹpẹ turari tí ó wà ní Jerusalẹmu, wọ́n dà wọ́n sí àfonífojì Kidironi. +Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrinla oṣù keji. Ojú ti àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn kò tíì ya ara wọn sí mímọ́, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n tètè lọ ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sí ilé OLUWA. +Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ara wọn sí ipò tí ó yẹ kí wọ́n wà, gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, eniyan Ọlọrun; àwọn alufaa bẹ̀rẹ̀ sí wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi sí orí pẹpẹ. +Àwọn tí wọn kò tíì ya ara wọn sí mímọ́ pọ̀ níbi àpéjọ náà, nítorí náà, àwọn ọmọ Lefi bá wọn pa ẹran wọn kí àwọn ẹran náà lè jẹ́ mímọ́ fún OLUWA. +Ogunlọ́gọ̀ eniyan, pataki jùlọ ọpọlọpọ ninu àwọn tí wọn wá láti Efuraimu, Manase, Isakari ati Sebuluni, kò tíì ya ara wọn sí mímọ́, sibẹ wọ́n jẹ àsè Àjọ Ìrékọjá, ṣugbọn kì í ṣe ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ṣugbọn Hesekaya gbadura fún wọn pé: “Kí OLUWA rere dáríjì gbogbo àwọn +tí wọ́n fi tọkàntọkàn wá OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má jẹ́ ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni wọ́n fi jẹ àsè àjọ náà gẹ́gẹ́ bí òfin ìwẹ̀nùmọ́ ti ibi mímọ́.” +Ọba, àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan ní Jerusalẹmu ti pinnu láti ṣe àjọ náà ní oṣù keji. +OLUWA gbọ́ adura Hesekaya, ó sì wo àwọn eniyan náà sàn. +Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu pa Àjọ Àìwúkàrà mọ́ fún ọjọ́ meje pẹlu ayọ̀ ńlá. Àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa ń kọrin ìyìn sí OLUWA lojoojumọ pẹlu gbogbo agbára wọn. +Hesekaya gba àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ṣe dáradára ninu iṣẹ́ OLUWA níyànjú. Àwọn eniyan náà jẹ àsè àjọ náà fún ọjọ́ meje, wọ́n ń rú ẹbọ alaafia, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. +Gbogbo wọn tún pinnu láti pa àjọ náà mọ́ fún ọjọ́ meje sí i, wọ́n sì fi tayọ̀tayọ̀ ṣe é. +Hesekaya, ọba fún àwọn eniyan náà ní ẹgbẹrun (1,000) akọ mààlúù ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan láti fi rúbọ. Àwọn ìjòyè náà fún àwọn eniyan ní ẹgbẹrun (1,000) akọ mààlúù, ati ẹgbaarun (10,000) aguntan. Ọpọlọpọ àwọn alufaa ni wọ́n wá, tí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́. +Gbogbo àwọn ará Juda, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn onílé ati àwọn àlejò tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Juda, gbogbo wọn ni wọ́n kún fún ayọ̀. +Gbogbo Jerusalẹmu kún fún ayọ̀ nítorí kò tíì tún sí irú rẹ̀ mọ́ láti ìgbà Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli. +Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi dìde, wọ́n súre fún àwọn eniyan; OLUWA gbọ́ ohùn wọn, adura wọn sì gòkè lọ sí ibùgbé mímọ́ rẹ̀ lọ́run. +Ṣugbọn wọn kò lè ṣe é ní àkókò rẹ̀ nítorí àwọn alufaa tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ kò tíì pọ̀ tó, àwọn eniyan kò sì tíì péjọ sí Jerusalẹmu tán. +Ìpinnu yìí dára lójú ọba ati gbogbo ìjọ eniyan. +Wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n kéde jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Israẹli láti Beeriṣeba títí dé Dani, pé kí àwọn eniyan wá sí Jerusalẹmu láti pa Àjọ Ìrékọjá mọ́ fún OLUWA Ọlọrun Israẹli; nítorí pé wọn kò tíì ṣe Àjọ Ìrékọjá náà pẹlu ọ̀pọ̀ eniyan gẹ́gẹ́ bí ìlànà. +Àwọn oníṣẹ́ lọ jákèjádò Israẹli ati Juda, pẹlu ìwé láti ọ̀dọ̀ ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba. Wọ́n kọ sinu ìwé náà pé: “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israẹli, kí ó lè pada sọ́dọ̀ ẹ̀yin tí ẹ kù tí ẹ sá àsálà, tí ọba Asiria kò pa. +Ẹ má dàbí àwọn baba yín ati àwọn arakunrin yín tí wọ́n ṣe alaiṣootọ sí OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, tí ó sì sọ ilẹ̀ wọn di ahoro bí ẹ ti rí i yìí. +Ẹ má ṣe oríkunkun, bí àwọn baba yín. Ẹ fi ara yín fún OLUWA, kí ẹ wá sí ibi mímọ́ rẹ̀, tí ó ti yà sọ́tọ̀ títí lae. Ẹ wá sin OLUWA Ọlọrun yín níbẹ̀, kí ibinu rẹ̀ lè yipada kúrò lọ́dọ̀ yín. +Bí ẹ bá pada sọ́dọ̀ OLUWA, àwọn arakunrin yín ati àwọn ọmọ yín yóo rí àánú lọ́dọ̀ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú, wọn yóo sì dá wọn pada sí ilẹ̀ yìí. Nítorí olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni OLUWA Ọlọrun yín, kò ní kẹ̀yìn si yín bí ẹ bá pada sọ́dọ̀ rẹ̀.” +Ìmúra fún Àjọ Ìrékọjá. +Nígbà tí wọ́n parí ayẹyẹ wọnyi, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá síbi àjọ náà lọ sí àwọn ìlú Juda, wọ́n fọ́ gbogbo òpó oriṣa, ati gbogbo igbó oriṣa Aṣera, wọ́n wó gbogbo àwọn pẹpẹ palẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Juda, ti Bẹnjamini, ti Efuraimu ati ti Manase. Nígbà tí wọ́n fọ́ gbogbo wọn túútúú tán, wọ́n pada lọ sí ìlú wọn, olukuluku sì lọ sí orí ilẹ̀ rẹ̀. +Asaraya, olórí alufaa, láti ìdílé Sadoku dá a lóhùn pé: “Láti ìgbà tí àwọn eniyan ti bẹ̀rẹ̀ sí mú ẹ̀bùn wá sí ilé OLUWA ni a ti ń jẹ àjẹyó, tí ó sì ń ṣẹ́kù, nítorí pé OLUWA ti bukun àwọn eniyan rẹ̀, ni a fi ní àjẹṣẹ́kù tí ó pọ̀ tó yìí.” +Hesekaya bá pàṣẹ pé kí wọ́n tọ́jú àwọn yàrá tó wà ninu ilé OLUWA, wọ́n bá ṣe ìtọ́jú wọn. +Wọ́n ṣolóòótọ́ ní kíkó àwọn ẹ̀bùn, ati ìdámẹ́wàá àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ náà pamọ́. Konanaya, ọmọ Lefi, ni olórí àwọn tí wọn ń bojútó wọn, Ṣimei, arakunrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀. +Jehieli, Asasaya, ati Nahati; Asaheli, Jerimotu, ati Josabadi; Elieli, Isimakaya, ati Mahati ati Bẹnaya ni àwọn alabojuto tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ Konanaya ati Ṣimei, arakunrin rẹ̀. Hesekaya ọba ati Asaraya olórí ilé OLUWA ni wọ́n yàn wọ́n sí iṣẹ́ náà. +Kore, ọmọ Imina, ọmọ Lefi kan tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn tẹmpili ni ó ń ṣe alákòóso ọrẹ àtinúwá tí wọ́n mú wá fún Ọlọrun. Òun ni ó sì ń pín àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA ati àwọn ọrẹ mímọ́ jùlọ. +Edẹni, Miniamini, ati Jeṣua, Ṣemaaya, Amaraya, ati Ṣekanaya, ń ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ìlú àwọn alufaa, wọ́n ń pín àwọn ẹ̀bùn náà láì ṣe ojuṣaaju àwọn arakunrin wọn, lọ́mọdé ati lágbà ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; +àfi àwọn ọkunrin, láti ẹni ọdún mẹta sókè, tí wọ́n ti kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé ìdílé, gbogbo awọn tí wọ́n wọ ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olukuluku ṣe gbà lójoojúmọ́, fun iṣẹ́ ìsìn wọn gẹ́gẹ́ bí ipò wọn, nípa ìpín wọn. +Wọ́n kọ orúkọ àwọn alufaa ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún sókè ni wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ipò wọn ati ìpín wọn. +Àwọn alufaa kọ orúkọ wọn sílẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, àwọn aya wọn, àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin gbogbo wọn patapata, nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nípa pípa ara wọn mọ́. +Ninu àwọn alufaa tí wọ́n wà ní ìlú àwọn ìran Aaroni ní ilẹ̀ gbogbogbòò ati ninu ìletò wọn, ni àwọn olóòótọ́ wà, tí wọ́n yàn láti máa pín oúnjẹ fún olukuluku ninu àwọn alufaa ati àwọn tí orúkọ wọn wà ninu àkọsílẹ̀ ìdílé àwọn Lefi. +Hesekaya pín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, olukuluku ní iṣẹ́ tirẹ̀. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wà fún ẹbọ sísun, ati ẹbọ alaafia. Àwọn náà ni wọ́n wà fún ati máa ṣe iṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ OLUWA, ati láti máa kọrin ọpẹ́ ati ìyìn sí OLUWA. +Jákèjádò Juda ni Hesekaya ti ṣe ètò yìí, ó ṣe ohun tí ó dára, tí ó tọ́, tí ó sì jẹ́ òtítọ́ lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀. +Gbogbo ohun tí ó ṣe ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òfin ati àṣẹ Ọlọ́run, ati wíwá tí ó wá ojurere Ọlọrun, gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe tọkàntọkàn, ó sì dára fún un. +Hesekaya a máa fa ẹran kalẹ̀ ninu agbo ẹran rẹ̀ fún ẹbọ sísun ti àárọ̀ ati ti àṣáálẹ́, ati fún ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ẹbọ oṣù tuntun ati àwọn ẹbọ mìíràn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA. +Ọba pàṣẹ fún àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé kí wọ́n mú ọrẹ tí ó tọ́ sí àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wa, kí wọ́n lè fi gbogbo àkókò wọn sílẹ̀ láti máa kọ́ àwọn eniyan ní òfin OLUWA. +Ní kété tí àṣẹ yìí tàn káàkiri, wọ́n mú ọpọlọpọ àkọ́so ọkà, ati ọtí ati òróró ati oyin, ati àwọn nǹkan irè oko mìíràn wá. Wọ́n tún san ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí wọ́n ní. +Àwọn ọmọ Israẹli ati ti Juda tí wọn ń gbé àwọn ìlú Juda náà san ìdámẹ́wàá mààlúù ati aguntan, ati ti àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun wọn, wọ́n kó wọn jọ bí òkítì. +Ní oṣù kẹta ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ìdámẹ́wàá náà jọ, wọ́n kó wọn jọ tán ní oṣù keje. +Nígbà tí Hesekaya ati àwọn ìjòyè wá wo àwọn ìdámẹ́wàá tí wọ́n kójọ bí òkítì, wọ́n yin OLUWA, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli. +Hesekaya bèèrè lọ́wọ́ àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi nípa àwọn òkítì náà. +Hesekaya Ṣe Àtúnṣe Ẹ̀sìn. +Lẹ́yìn gbogbo nǹkan tí Hesekaya ṣe, tí ó sin OLUWA pẹlu òtítọ́, Senakeribu ọba Asiria wá gbógun ti Juda. Ó dó ti àwọn ìlú olódi wọn, ó lérò pé òun óo jagun gbà wọ́n. +“Òun Senakeribu, ọba Asiria ní, kí ni wọ́n gbójú lé tí wọ́n fi dúró sí Jerusalẹmu, ìlú tí ogun dó tì? +Ó ní bí Hesekaya bá ní OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n lọ́wọ́ òun ọba Asiria, ó ń ṣì wọ́n lọ́nà ni, ó fẹ́ kí òùngbẹ ati ebi pa wọ́n kú ni. +Ó ní, Ṣebí Hesekaya yìí kan náà ni ó kó gbogbo oriṣa kúrò ní Jerusalẹmu ati ní Juda tí ó sọ fún wọn pé ibi pẹpẹ kan ṣoṣo ni wọ́n ti gbọdọ̀ máa jọ́sìn, kí wọn sì máa rúbọ níbẹ̀? +Ó ní ǹjẹ́ wọ́n mọ ohun tí òun ati baba òun ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn? Ati pé, ǹjẹ́ àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè náà gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria? +Ó ní èwo ni oriṣa wọn gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ òun, ninu gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi tí baba òun parun, tí Ọlọrun tiyín yóo fi wá gbà yín? +Ó ní nítorí náà, kí wọn má ṣe jẹ́ kí Hesekaya tàn wọ́n jẹ, tabi kí ó ṣì wọ́n lọ́nà báyìí. Ó ní kí wọn má gbọ́ ohun tí ó ń sọ rárá, nítorí pé kò sí oriṣa orílẹ̀-èdè kan tí ó tó gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ òun tabi lọ́wọ́ àwọn baba òun, kí á má wá sọ pé Ọlọrun tiwọn yóo gbà wọ́n lọ́wọ́ òun.” +Àwọn iranṣẹ ọba Asiria tún sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí OLUWA Ọlọrun ati sí Hesekaya, iranṣẹ rẹ̀. +Ọba Asiria yìí kọ àwọn ìwé àfojúdi kan sí OLUWA Ọlọrun Israẹli, ó ní, “Gẹ́gẹ́ bí àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kò ti lè gba àwọn eniyan wọn kúrò lọ́wọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun Hesekaya náà kò ní lè gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ mi.” +Àwọn iranṣẹ ọba Asiria kígbe sókè nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, sí àwọn ará Jerusalẹmu tí wọ́n wà lórí odi, wọn fi dẹ́rùbà wọ́n kí wọ́n lè gba ìlú náà. +Wọ́n sọ̀rọ̀ Ọlọrun Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn oriṣa àtọwọ́dá tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ń bọ. +Nígbà tí Hesekaya rí i pé Senakeribu ti pinnu láti gbógun ti Jerusalẹmu, +Hesekaya ati wolii Aisaya, ọmọ Amosi bá fi ìtara gbadura sí Ọlọrun nípa ọ̀rọ̀ yìí. +OLUWA bá rán angẹli kan lọ pa gbogbo akọni ọmọ ogun, ati àwọn ọ̀gágun ati àwọn olórí ogun Asiria ní ibùdó wọn. Nítorí náà, pẹlu ìtìjú ńlá ni Senakeribu fi pada lọ sí ìlú rẹ̀. Nígbà tí ó wọ inú ilé oriṣa lọ, àwọn kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin bá fi idà pa á. +Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe gba Hesekaya ati àwọn ará Jerusalẹmu sílẹ̀ lọ́wọ́ Senakeribu, ọba Asiria, ati gbogbo àwọn ọ̀tá Hesekaya, ó sì fún un ní alaafia. +Ọpọlọpọ eniyan mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA ní Jerusalẹmu, wọ́n sì mú ẹ̀bùn olówó iyebíye wá fún Hesekaya, ọba Juda. Láti ìgbà náà lọ, àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri bẹ̀rẹ̀ sí kókìkí rẹ̀. +Ní àkókò kan, Hesekaya ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ó gbadura, sí OLUWA, OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀, ó sì fún un ní àmì tí ó yani lẹ́nu kan, +ṣugbọn Hesekaya ṣe ìgbéraga, kò fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún ohun tí Ọlọrun ṣe fún un. Nítorí náà, inú bí OLUWA sí àtòun ati Juda ati Jerusalẹmu. +Hesekaya ati àwọn ará Jerusalẹmu bá rẹ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì ronupiwada. Nítorí náà, OLUWA kò bínú sí wọn mọ́ ní ìgbà ayé Hesekaya. +Hesekaya ní ọpọlọpọ ọrọ̀ ati ọlá. Ó kọ́ ilé ìṣúra tí ó kó fadaka, ati wúrà, ati òkúta olówó iyebíye, ati turari sí, ati apata ati gbogbo nǹkan olówó iyebíye. +Ó kọ́ àká fún ọkà, ọtí waini, ati òróró; ó ṣe ibùjẹ fún oríṣìíríṣìí mààlúù, ó sì ṣe ọgbà fún àwọn aguntan ati ewúrẹ́. +Bákan náà, ó kọ́ ọpọlọpọ ìlú fún ara rẹ̀, ó sì ní agbo ẹran lọpọlọpọ, nítorí Ọlọrun ti fún un ní ọrọ̀ lọpọlọpọ. +ó jíròrò pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ bí wọn yóo ti ṣe dí ìṣàn omi tí ó wà lẹ́yìn odi ìlú; wọ́n sì ràn án lọ́wọ́. +Hesekaya náà ló dí ẹnu odò Gihoni ní apá òkè, ó ya omi rẹ̀ wọ ìhà ìwọ̀ oòrùn ìlú Dafidi. Hesekaya sì ń ní ìlọsíwájú ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. +Nígbà tí àwọn olórí ilẹ̀ Babiloni ranṣẹ sí i láti mọ̀ nípa ohun ìyanu tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà, Ọlọrun fi sílẹ̀ láti dán an wò, kí Ọlọrun lè mọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀. +Àkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan yòókù tí Hesekaya ṣe, ati iṣẹ́ rere rẹ̀, wà ninu ìwé ìran wolii Aisaya, ọmọ Amosi ati ninu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati Israẹli. +Nígbà tí Hesekaya kú, wọ́n sin ín sí ara òkè, ninu ibojì àwọn ọmọ Dafidi. Gbogbo àwọn eniyan Juda ati ti Jerusalẹmu ṣe ẹ̀yẹ fún un. Manase, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Wọ́n kó ọpọlọpọ eniyan jọ, wọ́n dí àwọn orísun omi ati àwọn odò tí ń ṣàn ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ní, “Kò yẹ kí ọba Asiria wá, kí ó bá omi tí ó tó báyìí.” +Ọba yan àwọn òṣìṣẹ́ láti mọ gbogbo àwọn odi tí ó wó lulẹ̀, ati láti kọ́ ilé ìṣọ́ sí orí wọn. Wọ́n tún mọ odi mìíràn yípo wọn. Ó tún Milo tí ó wà ní ìlú Dafidi ṣe kí ó fi lágbára síi, ó sì pèsè ọpọlọpọ nǹkan ìjà ati apata. +Ọba yan àwọn ọ̀gágun lórí àwọn eniyan, ó sì pe gbogbo wọn jọ sí gbàgede ẹnubodè ìlú. Ó dá wọn lọ́kàn le, ó ní, +“Ẹ múra, ẹ ṣọkàn gírí. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà níwájú ọba Asiria ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀; nítorí agbára ẹni tí ó wà pẹlu wa ju ti àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lọ. +Agbára ti ẹran ara ni àwọn ọmọ ogun tirẹ̀ ní, ṣugbọn OLUWA Ọlọrun ni ó wà pẹlu wa láti ràn wá lọ́wọ́ ati láti jà fún wa.” Ọ̀rọ̀ tí Hesekaya ọba Juda sọ sì fi àwọn eniyan rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀. +Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Senakeribu ati àwọn ogun rẹ̀ gbógun ti Lakiṣi, ó ranṣẹ sí Hesekaya ọba Juda ati àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu pé, +Asiria Halẹ̀ Mọ́ Jerusalẹmu. +Ọmọ ọdún mejila ni Manase nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún marundinlọgọta. +OLUWA kìlọ̀ fún Manase ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́. +Nítorí náà, OLUWA mú kí ọ̀gágun ilẹ̀ Asiria wá ṣẹgun Juda, wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà de Manase, wọ́n fi ìwọ̀ mú un, wọ́n sì fà á lọ sí Babiloni. +Nígbà tí ó wà ninu ìpọ́njú ó wá ojurere OLUWA Ọlọrun, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ patapata níwájú Ọlọrun àwọn baba rẹ̀. +Ó gbadura sí OLUWA, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, ó sì mú un pada wá sórí ìtẹ́ rẹ̀ ní Jerusalẹmu. Ó wá mọ̀ nígbà náà pé OLUWA ni Ọlọrun. +Lẹ́yìn náà ó mọ odi ìta sí ìlú Dafidi, ní apá ìwọ̀ oòrùn Gihoni, ní àfonífojì, ati sí ẹnubodè ẹja; ó mọ ọ́n tí ó ga yípo Ofeli. Ó kó àwọn ọ̀gágun sinu àwọn ìlú olódi ní Juda. +Ó kó àwọn oriṣa ati àwọn ère kúrò ninu ilé OLUWA, ati gbogbo ojúbọ oriṣa tí ó kọ́ sórí òkè níbi tí ilé OLUWA wà, ati àwọn tí wọ́n kọ́ káàkiri gbogbo ìlú Jerusalẹmu. Ó da gbogbo wọn sẹ́yìn odi ìlú. +Ó tún pẹpẹ OLUWA tẹ́ sí ipò rẹ̀, ó rú ẹbọ alaafia ati ẹbọ ọpẹ́ lórí rẹ̀, ó sì pàṣẹ fún àwọn eniyan Juda pé kí wọ́n máa sin OLUWA Ọlọrun Israẹli. +Sibẹsibẹ àwọn eniyan ṣì ń rúbọ ní àwọn ibi ìrúbọ, ṣugbọn OLUWA Ọlọrun wọn ni wọ́n ń rúbọ sí. +Àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yòókù tí Manase ṣe, ati adura rẹ̀ sí Ọlọrun, ati àwọn ọ̀rọ̀ tí aríran sọ fún un ní orúkọ OLUWA, Ọlọrun Israẹli, gbogbo rẹ̀ wà ninu ìwé ìtàn àwọn ọba Israẹli. +Adura rẹ̀ sí Ọlọrun, ati bí Ọlọrun ṣe dá a lóhùn, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ati aiṣododo rẹ̀, wà ninu ìwé Ìtàn Àwọn Aríran. Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo ibi tí ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀ sí, àwọn ère tí ó gbẹ́ fún Aṣera, ati àwọn ère tí ó ń sìn kí ó tó ronupiwada. +Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA. Gbogbo nǹkan ẹ̀gbin tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde fún àwọn ọmọ Israẹli máa ń ṣe ni òun náà ṣe. +Nígbà tí ó kú, wọ́n sin ín sí ààfin rẹ̀. Amoni, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ọmọ ọdún mejilelogun ni Amoni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji ní Jerusalẹmu. +Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, bíi Manase, baba rẹ̀, ó rúbọ sí gbogbo oriṣa tí baba rẹ̀ ṣe, ó sì ń bọ wọ́n. +Kò fi ìgbà kankan ronupiwada bí baba rẹ̀ ti ṣe níwájú OLUWA. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ń dá kún ẹ̀ṣẹ̀. +Nígbà tí ó yá, àwọn ọ̀gágun rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀. +Ṣugbọn gbogbo àwọn ará ilẹ̀ Juda pa àwọn tí wọ́n pa Amoni ọba, wọ́n sì fi Josaya ọmọ rẹ̀ jọba. +Gbogbo ibi ìrúbọ tí Hesekaya, baba rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ó tún kọ́. Ó tẹ́ pẹpẹ fún Baali, ó sì ri àwọn òpó fún Aṣera. Ó ń bọ àwọn ìràwọ̀, ó sì ń sìn wọ́n. +Ó tẹ́ pẹpẹ oriṣa sinu ilé OLUWA, ilé tí OLUWA ti sọ nípa rẹ̀ pé, “Ní Jerusalẹmu ni ibi ìjọ́sìn tí orúkọ mi yóo wà, tí ẹ óo ti máa sìn mí títí lae.” +Ó tẹ́ pẹpẹ sinu gbọ̀ngàn meji tí ó wà ninu tẹmpili, wọ́n sì ń bọ àwọn ìràwọ̀ ati gbogbo ohun tí ó wà lójú ọ̀run níbẹ̀. +Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun ní àfonífojì ọmọ Hinomu. Ó ń lo àfọ̀ṣẹ, ó ń woṣẹ́, a sì máa lọ sọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀. Ó dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA tóbẹ́ẹ̀ tí inú OLUWA fi bẹ̀rẹ̀ sí ru. +Ó gbé ère oriṣa tí ó gbẹ́ wá sí ilé Ọlọrun, ilé tí Ọlọrun ti sọ nípa rẹ̀ fún Dafidi ati Solomoni, ọmọ rẹ̀ pé, “Ninu ilé yìí ati ní Jerusalẹmu tí mo ti yàn láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila ni wọn yóo ti máa sìn mí. +Bí àwọn ọmọ Israẹli bá pa òfin mi mọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà ati ìdájọ́ mi tí mo fún wọn láti ọwọ́ Mose, n kò ní ṣí wọn nídìí mọ́ lórí ilẹ̀ tí mo ti yàn fún àwọn baba wọn.” +Manase ṣi àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu lọ́nà, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ṣe burúkú ju àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA parun fún Israẹli lọ. +Manase, Ọba Juda. +Ọmọ ọdún mẹjọ ni Josaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanlelọgbọn. +Wọ́n kó owó náà fún àwọn tí ń ṣe àbojútó iṣẹ́ náà. Àwọn ni wọ́n ń sanwó fún àwọn tí wọn ń tún ilé OLUWA ṣe. +Wọ́n sanwó fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn tí wọn ń mọlé, láti ra òkúta gbígbẹ́ ati pákó ati igi, kí wọ́n fi tún àwọn ilé tí àwọn ọba Juda ti sọ di àlàpà kọ́. +Àwọn eniyan náà fi òtítọ́ inú ṣe iṣẹ́ náà. Àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣàkóso wọn ni: Jahati ati Ọbadaya, láti inú ìran Merari, ati Sakaraya ati Meṣulamu, láti inú ìran Kohati. Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n mọ̀ nípa ohun èlò orin +ni wọ́n ń ṣàkóso àwọn tí wọn ń ru ẹrù, ati àwọn tí wọn ń ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ mìíràn. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ Lefi jẹ́ akọ̀wé, àwọn kan wà nídìí ètò ìsìn, àwọn mìíràn sì jẹ́ aṣọ́nà. +Nígbà tí wọn ń kó owó tí àwọn eniyan ti mú wá sinu ilé OLUWA jáde, Hilikaya, alufaa rí ìwé òfin OLUWA tí Ọlọrun fún Mose. +Hilikaya sọ fún Ṣafani akọ̀wé, ó ní, “Mo rí ìwé òfin ninu ilé OLUWA.” Ó fún Ṣafani ní ìwé náà, +Ṣafani sì mú un lọ sọ́dọ̀ ọba, ó ní, “Àwọn iranṣẹ ń ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àṣẹ rẹ. +Wọ́n ti kó owó tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA jọ, wọ́n sì ti kó o fún àwọn tí wọn ń ṣe àkóso iṣẹ́ náà ati àwọn òṣìṣẹ́;” +ati pé, “Hilikaya, alufaa, fún mi ní ìwé kan.” Ṣafani sì kà á níwájú ọba. +Nígbà tí ọba gbọ́ ohun tí ó wà ninu ìwé òfin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbẹ̀rù ati ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. +Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA. Ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ Dafidi, baba ńlá rẹ̀, nípa títẹ̀lé òfin Ọlọrun fínnífínní. +Ó pàṣẹ fún Hilikaya, Ahikamu, ọmọ Ṣafani, Abidoni, ọmọ Mika, ati Ṣafani, akọ̀wé, ati Asaya, iranṣẹ ọba, pé, +“Ẹ tọ Ọlọrun lọ fún èmi ati àwọn eniyan tí wọ́n kù ní Juda ati ní Israẹli, ẹ ṣe ìwádìí ohun tí a kọ sinu ìwé náà; nítorí pé àwọn baba ńlá wa tàpá sí ọ̀rọ̀ OLUWA, wọn kò sì ṣe ohun tí a kọ sinu ìwé yìí ni OLUWA ṣe bínú sí wa lọpọlọpọ.” +Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, Hilikaya ati àwọn tí wọ́n tẹ̀lé e, lọ sọ́dọ̀ Hulida, wolii obinrin, iyawo Ṣalumu, ọmọ Tokihati, ọmọ Hasira tí ó jẹ́ alabojuto ibi tí wọn ń kó aṣọ pamọ́ sí ní ìhà keji Jerusalẹmu tí Hulida ń gbé. Wọ́n sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un. +Ó bá dá wọn lóhùn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí n sọ fun yín, kí ẹ sọ fún ẹni tí ó ran yín sí mi pé +òun OLUWA ní òun óo mú ibi wá sórí ibí yìí ati àwọn eniyan ibẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé tí a kà sí ọba Juda létí. +Nítorí pé wọ́n ti kọ òun OLUWA sílẹ̀, wọ́n sì ń sun turari sí àwọn oriṣa, kí wọ́n lè fi ìṣe wọn mú òun bínú; nítorí náà òun óo bínú sí ibí yìí, kò sí ẹni tí yóo lè dá ibinu òun dúró. +Ó ní kí ẹ sọ ohun tí ẹ ti gbọ́ fún ọba Juda tí ó ranṣẹ láti wá wádìí lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun pé, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, +nítorí pé nígbà tí ó gbọ́ nípa ìyà tí n óo fi jẹ Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ibẹ̀, ó ronupiwada, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọkún níwájú mi, mo sì ti gbọ́ adura rẹ̀. +Nítorí náà, ìdájọ́ tí mo ti pinnu sórí Jerusalẹmu kò ní ṣẹlẹ̀ ní ìgbà ayé rẹ̀, ikú wọ́ọ́rọ́ ni yóo sì kú.”Àwọn eniyan náà bá pada lọ jíṣẹ́ fún ọba. +Lẹ́yìn náà, Josaya ọba ranṣẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà Juda ati ti Jerusalẹmu. +Ní ọdún kẹjọ tí Josaya gorí oyè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọde ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí sin Ọlọrun Dafidi, baba ńlá rẹ̀. Ní ọdún kejila, ó bẹ̀rẹ̀ sí wó àwọn pẹpẹ oriṣa ní gbogbo ilẹ̀ Juda ati Jerusalẹmu. Ó wó àwọn òpó oriṣa Aṣera, ó sì fọ́ àwọn ère gbígbẹ́ ati èyí tí wọ́n rọ. +Ó bá lọ sí ilé OLUWA pẹlu gbogbo ará Juda, ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu; ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi ati àwọn eniyan yòókù; ati olówó ati talaka. Ọba ka ìwé majẹmu tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA sí etígbọ̀ọ́ wọn. +Ó dúró ní ààyè rẹ̀, ó sì bá OLUWA dá majẹmu pé òun óo máa fi tọkàntọkàn rìn ní ọ̀nà OLUWA, òun óo máa pa òfin rẹ̀ mọ́, òun óo máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ, òun ó sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ̀. Ó ní òun ó máa fi tọkàntọkàn pa majẹmu tí a kọ sinu ìwé náà mọ́. +Lẹ́yìn náà, ó ní kí àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ati àwọn ará Jerusalẹmu bá OLUWA dá majẹmu kí wọ́n sì pa á mọ́. Àwọn ará Jerusalẹmu sì pa majẹmu OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn mọ́. +Josaya run gbogbo àwọn ère oriṣa tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, ó sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli sin OLUWA Ọlọrun wọn. Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, wọn kò yipada kúrò lẹ́yìn OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. +Wọ́n wó àwọn oriṣa Baali lulẹ̀ níwájú rẹ̀; ó fọ́ àwọn pẹpẹ turari tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó wó àwọn òpó oriṣa Aṣera ati gbogbo àwọn ère tí wọ́n fi igi gbẹ́ ati àwọn tí wọ́n fi irin rọ. Ó fọ́ wọn túútúú, ó sì fọ́n wọn ká sórí ibojì àwọn tí wọn ń sìn wọ́n. +Ó sun egungun àwọn babalóòṣà lórí pẹpẹ oriṣa wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe fọ Jerusalẹmu ati Juda mọ́ tónítóní. +Bákan náà ni ó ṣe ní àwọn ìlú Manase, ati ti Efuraimu, ati àwọn ìlú ilẹ̀ Simeoni títí dé ilẹ̀ Nafutali, ati ní gbogbo àyíká wọn. +Ó wó àwọn pẹpẹ, ó lọ àwọn òpó Aṣera ati àwọn ère oriṣa lúúlúú, ó sì wó gbogbo pẹpẹ turari jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Lẹ́yìn náà ó pada sí Jerusalẹmu. +Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Josaya, lẹ́yìn tí ó ti pa ìbọ̀rìṣà rẹ́ ní ilẹ̀ náà, ó rán Ṣafani ọmọ Asalaya láti tún ilé OLUWA Ọlọrun rẹ̀ ṣe pẹlu Maaseaya, gomina ìlú, ati Joa, ọmọ Joahasi tí ó jẹ́ alákòóso ìwé ìrántí. +Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Hilikaya, olórí alufaa, wọ́n kó owó tí àwọn eniyan mú wá sí ilé OLUWA fún un, tí àwọn Lefi tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà gbà lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Manase, ati Efuraimu ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yòókù, ati lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń gbé Juda, Bẹnjamini ati Jerusalẹmu. +Josaya, Ọba Juda. +Josaya ṣe Àjọ Ìrékọjá fún OLUWA ní Jerusalẹmu. Ní ọjọ́ kẹrinla, oṣù kinni ni wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá. +Nígbà tí gbogbo ètò ti parí, àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi dúró ní ààyè wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí ọba pa. +Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá, àwọn alufaa wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lára àwọn ẹran náà sórí pẹpẹ, àwọn ọmọ Lefi sì bó awọ àwọn ẹran náà. +Wọ́n ya ẹbọ sísun sọ́tọ̀ kí wọ́n lè pín wọn fún gbogbo ìdílé tí ó wà níbẹ̀, kí wọ́n lè fi rúbọ sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe pẹlu àwọn mààlúù. +Wọ́n sun ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Wọ́n bọ ẹran ẹbọ mímọ́ ninu ìkòkò, ìsaasùn ati apẹ, wọ́n sì pín in fún àwọn eniyan lẹsẹkẹsẹ. +Lẹ́yìn náà, wọ́n tọ́jú tiwọn ati ti àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni. Nítorí iṣẹ́ ṣíṣe kò jẹ́ kí àwọn alufaa rí ààyè, láti àárọ̀ títí di alẹ́. Wọ́n ń rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ń sun ọ̀rá ẹran níná. Nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi fi tọ́jú tiwọn, tí wọ́n sì tọ́jú ti àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni. +Àwọn akọrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Asafu dúró ní ipò wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dafidi. Bẹ́ẹ̀ náà ni Asafu, Hemani, ati Jedutuni, aríran ọba. Àwọn aṣọ́nà tẹmpili kò kúrò ní ààyè wọn, nítorí pé àwọn ọmọ Lefi ti tọ́jú ẹbọ ìrékọjá tiwọn fún wọn. +Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìsìn Àjọ Ìrékọjá ati ti ẹbọ sísun lórí pẹpẹ OLUWA ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Josaya ọba. +Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá ṣe àsè Àjọ Ìrékọjá, wọ́n sì ṣe Àjọ Àìwúkàrà fún ọjọ́ meje. +Kò tíì sí irú àsè Àjọ Ìrékọjá bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli láti ìgbà ayé wolii Samuẹli. Kò sì tíì sí ọba kankan ní Israẹli tí ó tíì ṣe àsè Àjọ Ìrékọjá bí Josaya ti ṣe pẹlu àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn eniyan Juda, àwọn tí wọ́n wá láti Israẹli ati àwọn ará Jerusalẹmu. +Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Josaya ni wọ́n ṣe Àjọ Ìrékọjá yìí. +Ó yan àwọn alufaa sí ipò wọn, ó sì gbà wọ́n níyànjú kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn ninu ilé OLUWA. +Nígbà tí ó yá lẹ́yìn tí Josaya ti ṣe ètò inú tẹmpili tán, Neko, ọba Ijipti wá jagun ní Kakemiṣi, ní odò Yufurate. Josaya sì digun lọ bá a jà. +Neko rán ikọ̀ sí Josaya pé, “Kí ló lè fa ìjà láàrin wa, ìwọ ọba Juda? Ìwọ kọ́ ni mo wá bá jà lákòókò yìí, orílẹ̀-èdè tí èmi pẹlu rẹ̀ ní ìjà ni mo wá bá jà. Ọlọrun ni ó sì sọ fún mi pé kí n má jáfara, má ṣe dojú ìjà kọ Ọlọrun, nítorí pé ó wà pẹlu mi; kí ó má ba à pa ọ́ run.” +Ṣugbọn Josaya ṣe oríkunkun, ó paradà kí wọ́n má baà dá a mọ̀, ó lọ bá a jà. Kò fetí sí ọ̀rọ̀ Neko, tí Ọlọrun sọ, ó lọ bá Neko jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Megido. +Àwọn tafàtafà ta Josaya ọba ní ọfà, ó bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé mi kúrò lójú ogun, nítorí mo ti fara gbọgbẹ́, ọgbẹ́ náà sì pọ̀.” +Nítorí náà, wọ́n gbé e kúrò ninu kẹ̀kẹ́ ogun tí ó wà tẹ́lẹ̀ sinu òmíràn, wọ́n sì gbé e lọ sí Jerusalẹmu. Ó kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalẹmu ṣe ọ̀fọ̀ rẹ̀. +Wolii Jeremaya kọ orin arò fún Josaya ọba. Ó ti di àṣà ní Israẹli fún àwọn akọrin, lọkunrin ati lobinrin láti máa mẹ́nu ba Josaya nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń kọrin arò. +Àkọsílẹ̀ gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Josaya ṣe ati iṣẹ́ rere rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin OLUWA, +gbogbo ohun tí ó ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli ati ti Juda. +Ó sọ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń kọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n sì jẹ́ mímọ́ pé, “Ẹ gbé Àpótí mímọ́ náà sinu ilé tí Solomoni ọmọ Dafidi, ọba Israẹli kọ́. Ẹ kò ní máa gbé e lé èjìká kiri mọ́. Ṣugbọn kí ẹ máa ṣiṣẹ́ fún OLUWA Ọlọrun, ati fún gbogbo eniyan Israẹli. +Ẹ kó ara yín jọ ní ìdílé ìdílé ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Dafidi, ọba Israẹli ati ti Solomoni ọmọ rẹ̀. +Ẹ dúró ní ibi mímọ́, kí ẹ sì pín ara yín sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé àwọn arakunrin yín. Ìdílé kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ ní àwọn ọmọ Lefi tí wọn yóo wà pẹlu wọn. +Kí ẹ pa ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ múra sílẹ̀ fún àwọn arakunrin yín láti ṣe ohun tí OLUWA sọ láti ẹnu Mose.” +Josaya ọba fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ ní ẹran fún ẹbọ Ìrékọjá. Láti inú agbo ẹran tirẹ̀ ni ó ti mú ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) aguntan ati ọmọ ewúrẹ́, ati ẹgbẹẹdogun (3,000) mààlúù fún wọn. +Àwọn olóyè náà fi tọkàntọkàn fún àwọn eniyan, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní nǹkan. Hilikaya, Sakaraya ati Jehieli, àwọn alákòóso ninu ilé Ọlọrun, fún àwọn alufaa ní ẹgbẹtala (2,600) ọ̀dọ́ aguntan ati ọmọ ewúrẹ́ ati ọọdunrun (300) mààlúù fún ẹbọ Ìrékọjá. +Àwọn olórí ninu àwọn ọmọ Lefi: Konanaya pẹlu Ṣemaaya ati Netaneli, àwọn arakunrin rẹ̀; ati Haṣabaya, Jeieli, ati Josabadi, àwọn olóyè ninu ọmọ Lefi dá ẹẹdẹgbaata (5,000) ọ̀dọ́ aguntan, ati ọmọ ewúrẹ́, ati ẹẹdẹgbẹta (500) mààlúù fún àwọn ọmọ Lefi kí wọn fi rú ẹbọ Ìrékọjá. +Josaya Pa Àjọ Ìrékọjá Mọ́. +Àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda bá fi Joahasi, ọmọ Josaya, jọba ní Jerusalẹmu lẹ́yìn baba rẹ̀. +Nígbà tí ọdún yípo, Nebukadinesari, ọba Babiloni ranṣẹ lọ mú un wá sí Babiloni pẹlu àwọn ohun èlò olówó iyebíye tí ó wà ninu ilé OLUWA. Ó sì fi Sedekaya, arakunrin rẹ̀ jọba ní Jerusalẹmu ati Juda. +Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. +Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀, kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú wolii Jeremaya ẹni tí Ọlọrun rán sí i láti bá a sọ̀rọ̀. +Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinesari, bẹ́ẹ̀ sì ni Nebukadinesari ti fi ipá mú un búra ní orúkọ OLUWA pé kò ní ṣọ̀tẹ̀ sí òun. Ó ṣoríkunkun, ó sì kọ̀ láti yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. +Bákan náà, àwọn alufaa tí wọ́n jẹ́ aṣaaju ati àwọn eniyan yòókù pàápàá ṣe aiṣootọ sí OLUWA, wọ́n tẹ̀lé ìwà ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká, wọ́n sì sọ ilé tí OLUWA ti yà sí mímọ́ ní Jerusalẹmu di aláìmọ́. +OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn kò dẹ́kun láti máa rán wolii sí wọn, nítorí pé àánú àwọn eniyan rẹ̀ ati ibùgbé rẹ̀ ń ṣe é. +Ṣugbọn, yẹ̀yẹ́ ni wọ́n ń fi àwọn iranṣẹ Ọlọrun ṣe. Wọn kò náání ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń kẹ́gàn àwọn wolii rẹ̀ títí tí OLUWA fi bínú sí wọn, débi pé kò sí àtúnṣe. +Ọlọrun mú kí ọba Kalidea gbógun tì wọ́n. Ọba náà fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin Juda ninu tẹmpili, kò ṣàánú àwọn ọdọmọkunrin tabi wundia, tabi àwọn àgbà tabi arúgbó; gbogbo wọn ni Ọlọrun fi lé e lọ́wọ́. +Ọba Babiloni kó gbogbo ohun èlò ilé OLUWA, ati ńláńlá, ati kéékèèké, ati àwọn ìṣúra tí ó wà níbẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní ààfin ati ti ilé àwọn ìjòyè; ó kó gbogbo wọn patapata lọ sí Babiloni. +Wọ́n jó ilé OLUWA, wọ́n w�� odi Jerusalẹmu, wọ́n jó ààfin ọba, wọ́n sì ba gbogbo nǹkan olówó iyebíye ibẹ̀ jẹ́. +Joahasi jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelogun nígbà tí ó jọba, ó wà lórí oyè fún oṣù mẹta. +Nebukadinesari kó gbogbo àwọn tí wọ́n kù tí wọn kò pa lẹ́rú, ati àwọn ọmọ wọn. Ó kó wọn lọ sí Babiloni, wọ́n sì ń sin òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ títí di àkókò ìjọba Pasia; +kí ohun tí OLUWA ti sọ láti ẹnu wolii Jeremaya lè ṣẹ, pé, “Ilẹ̀ náà yóo di ahoro fún aadọrin ọdún kí ó lè ní gbogbo ìsinmi tí ó yẹ kí ó ti ní, ṣugbọn tí kò ní.” +Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Pasia, OLUWA mú ohun tí ó ti sọ láti ẹnu wolii Jeremaya ṣẹ. OLUWA fi sí Kirusi lọ́kàn, ó sì pàṣẹ jákèjádò ìjọba rẹ̀. Ó kọ àṣẹ náà sílẹ̀ báyìí pé: +“Èmi Kirusi, ọba Pasia, ni mo pàṣẹ yìí pé, ‘OLUWA Ọlọrun ọ̀run ni ó fún mi ní ìjọba lórí gbogbo ayé, òun ni ó sì ti pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé kan fún òun ní Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda. Nítorí náà, gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ́ tirẹ̀ lára yín, kí wọ́n lọ sibẹ, kí OLUWA Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn.’ ” +Ọba Ijipti ni ó lé e kúrò lórí oyè ní Jerusalẹmu, ó sì mú àwọn ọmọ Juda ní ipá láti máa san ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ati ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, gẹ́gẹ́ bí ìṣákọ́lẹ̀. +Neko, ọba Ijipti fi Eliakimu, arakunrin Joahasi jọba lórí Jerusalẹmu ati Juda, ó yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jehoiakimu, ó sì mú Joahasi lọ sí Ijipti. +Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Jehoiakimu nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀. +Nebukadinesari, ọba Babiloni, gbógun tì í, ó sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, ó fà á lọ sí Babiloni. +Nebukadinesari, ọba Babiloni, kó ninu àwọn ohun èlò ilé OLUWA lọ sí Babiloni, ó kó wọn sinu ààfin rẹ̀ ní Babiloni. +Àkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoiakimu ṣe ati gbogbo ohun ìríra tí ó ṣe, ati àwọn àìdára rẹ̀ wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli ati ti Juda. Jehoiakini, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Jehoiakini jẹ́ ọmọ ọdún mẹjọ nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè fún oṣù mẹta ati ọjọ́ mẹ́wàá ní Jerusalẹmu. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA. +Joahasi, ọba Juda. +Solomoni ọba ṣe pẹpẹ idẹ kan tí ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9), ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó ga ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½). +Ó gbé agbada omi kalẹ̀ sí apá gúsù ìhà ìlà oòrùn igun ilé náà. +Huramu mọ ìkòkò, ó rọ ọkọ́, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó ṣe sinu ilé Ọlọrun fún Solomoni ọba. +Àwọn iṣẹ́ náà nìwọ̀nyí: Òpó meji, àwọn ọpọ́n meji tí wọ́n dàbí abọ́ tí wọ́n wà lórí àwọn òpó náà, nǹkankan tí ó dàbí ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dárà sára àwọn ọpọ́n tí ó wà lórí òpó náà, +àwọn irinwo òdòdó idẹ tí wọ́n fi ṣe ọnà ní ìlà meji meji yí ọpọ́n orí àwọn òpó náà ká. +Ó ṣe àwọn abọ́ ńlá ati ìjókòó wọn. +Ó ṣe agbada omi kan ati ère mààlúù mejila sí abẹ́ rẹ̀. +Ó mọ àwọn ìkòkò, ó rọ ọkọ́ ati àmúga tí wọ́n fi ń mú ẹran, ati gbogbo ohun èlò wọn. Idẹ dídán ni Huramu fi ṣe gbogbo wọn fún Solomoni ọba, fún lílò ninu ilé OLUWA. +Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọdani tí ó jẹ́ ilẹ̀ amọ̀, láàrin Sukotu ati Sereda ni ọba ti ṣe wọ́n. +Àwọn nǹkan tí Solomoni ṣe pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí a kò fi mọ ìwọ̀n idẹ tí ó lò. +Solomoni ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ilé Ọlọrun: pẹpẹ wúrà, tabili fún burẹdi ìfihàn. +Ó ṣe agbada omi kan tí ó fẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½), ó sì ga ní igbọnwọ marun-un (mita 2¼). Àyíká etí rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 13½). +Àwọn ọ̀pá ati fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe láti máa jò níwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ. +Ó fi wúrà tí ó dára jùlọ ṣe àwọn òdòdó, àwọn fìtílà ati àwọn ẹ̀mú. +Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ohun tí wọ́n fi ń tún òwú fìtílà ṣe ati àwọn àwo kòtò; àwọn àwo turari, ati àwọn àwo ìmúná. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn ìta tẹmpili, ati ìlẹ̀kùn síbi mímọ́ jùlọ, ati ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn tẹmpili náà. +Gbogbo ẹ̀yìn agbada yìí ni ó ya àwòrán mààlúù sí ní ìlà meji meji yíká ìsàlẹ̀ etí rẹ̀. +Agbada yìí wà lórí ère mààlúù mejila tí wọ́n kọjú síta: mẹta kọjú sí ìhà àríwá, mẹta kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹta kọjú sí ìhà gúsù, mẹta yòókù sì kọjú sí ìlà oòrùn. +Agbada náà nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ dàbí etí ife omi ati bí òdòdó lílì. Agbada náà gbà tó ẹgbẹẹdogun ìwọ̀n bati omi. +Ó ṣe abọ́ ńlá mẹ́wàá, ó gbé marun-un ka ẹ̀gbẹ́ gúsù, ó sì gbé marun-un yòókù ka ẹ̀gbẹ́ àríwá. Àwọn abọ́ wọnyi ni wọ́n fi ń bu omi láti fọ àwọn ohun tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Omi inú agbada náà sì ni àwọn alufaa máa ń lò láti fi wẹ̀. +Solomoni ṣe ọ̀pá fìtílà wúrà mẹ́wàá bí àpẹẹrẹ tí wọ́n fún un. Ó gbé wọn kalẹ̀ ninu tẹmpili: marun-un ní ìhà gúsù, marun-un yòókù ní ìhà àríwá. +Ó ṣe tabili mẹ́wàá, ó gbé wọn kalẹ̀ ninu tẹmpili: marun-un ní ìhà gúsù, marun-un yòókù ní ìhà àríwá. Ó sì ṣe ọgọrun-un àwo kòtò wúrà. +Ó kọ́ gbọ̀ngàn kan fún àwọn alufaa, ati òmíràn tí ó tóbi, ó ṣe ìlẹ̀kùn sí wọn, ó sì yọ́ idẹ bo àwọn ìlẹ̀kùn náà. +Àwọn Ohun Èlò Inú Tẹmpili. +Nígbà tí Solomoni ọba parí gbogbo iṣẹ́ ilé OLUWA, ó kó gbogbo nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá sinu ilé Ọlọrun: àwọn nǹkan bíi fadaka, wúrà, ati gbogbo ohun èlò, ó pa wọ́n mọ́ ninu àwọn ilé ìṣúra tí wọ́n wà níbẹ̀. +Ohun kan ṣoṣo tí ó wà ninu àpótí náà ni tabili meji tí Mose kó sibẹ ní òkè Horebu, níbi tí Ọlọrun ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti. +Gbogbo àwọn alufaa jáde wá láti ibi mímọ́, (nítorí gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà níbẹ̀ ti ya ara wọn sí mímọ́ láìbèèrè ìpín tí olukuluku wà. +Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni, àwọn ọmọkunrin wọn ati àwọn ìbátan wọn dúró ní apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ. Wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, wọ́n ń fi ìlù, hapu ati dùùrù kọrin; pẹlu ọgọfa alufaa tí wọ́n ń fi fèrè kọrin, +àwọn onífèrè ati àwọn akọrin pa ohùn pọ̀ wọ́n ń kọ orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí OLUWA). Wọ́n ń fi fèrè ati ìlù ati àwọn ohun èlò orin mìíràn kọrin ìyìn sí OLUWA pé:“OLUWA ṣeun,ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ kò lópin.”Ìkùukùu kún inú tẹmpili OLUWA, +tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, nítorí ògo OLUWA tí ó kún ilé Ọlọrun. +Lẹ́yìn náà, Solomoni pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, àwọn olórí ẹ̀yà, ati àwọn baálé baálé ní ìdílé Israẹli ati ti Jerusalẹmu, láti gbé àpótí majẹmu OLUWA láti Sioni, ìlú Dafidi, wá sinu tẹmpili. +Gbogbo wọn péjọ sọ́dọ̀ ọba ní àkókò àjọ̀dún, ní oṣù keje. +Nígbà tí àwọn àgbààgbà péjọ tán, àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí náà. +Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí náà wá pẹlu àgọ́ àjọ, ati gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà ninu àgọ́ àjọ náà. +Solomoni ọba ati gbogbo ìjọ Israẹli dúró níwájú àpótí majẹmu, wọ́n ń fi ọpọlọpọ aguntan ati ọpọlọpọ mààlúù tí kò níye rúbọ. +Àwọn alufaa gbé àpótí majẹmu OLUWA wá sí ààyè rẹ̀ ninu tẹmpili ní ibi mímọ́ jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ àwọn ìyẹ́ kerubu. +Àwọn kerubu na àwọn ìyẹ́ wọn sórí ibi tí àpótí náà wà tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bo àpótí náà ati àwọn òpó rẹ̀. +Àwọn ọ̀pá náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi lè rí orí wọn láti ibi mímọ́ jùlọ, ṣugbọn wọn kò lè rí wọn láti ìta. Wọ́n wà níbẹ̀ títí di òní olónìí. +Gbígbé Àpótí Ẹ̀rí Wá sinu Tẹmpili. +Solomoni ọba ní,“OLUWA, o ti sọ pé o óo máa gbé inú òkùnkùn biribiri. +“Nisinsinyii OLUWA ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Mo ti wà ní ipò baba mi, mo ti gorí ìtẹ́ ọba Israẹli, bí OLUWA ti ṣèlérí, mo sì ti kọ́ tẹmpili fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. +Mo ti gbé àpótí ẹ̀rí sibẹ, inú rẹ̀ sì ni majẹmu tí OLUWA bá àwọn eniyan Israẹli dá wà.” +Lẹ́yìn náà, Solomoni dúró níwájú pẹpẹ lójú gbogbo eniyan, ó gbé ọwọ́ mejeeji sókè, ó sì gbadura sí Ọlọrun. +Solomoni ti ṣe pẹpẹ bàbà kan, ó gbé e sí àgbàlá ilé náà. Gígùn ati ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹta (1.3 mita). Solomoni gun orí pẹpẹ yìí, níbi tí gbogbo eniyan ti lè rí i. Ó kúnlẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Ọlọrun; +ó bá gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun tí ó dàbí rẹ ní ọ̀run tabi ní ayé, ìwọ tí ò ń pa majẹmu mọ́, tí o sì ń fi ìfẹ́ ńlá han àwọn iranṣẹ rẹ, tí wọn ń fi tọkàntọkàn tẹ̀lé ìlànà rẹ. +O ti mú ìlérí rẹ ṣẹ fún baba mi, Dafidi, iranṣẹ rẹ. O fi ẹnu rẹ ṣèlérí, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú ìlérí náà ṣẹ lónìí. +Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun Israẹli, jé�� kí ìlérí tí o ṣe fún Dafidi, baba mi ṣẹ, pé, ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba ní Israẹli títí lae, bí wọn bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣe. +Nisinsinyii, jọ̀wọ́ Ọlọrun Israẹli, mú ọ̀rọ̀ rẹ tí o sọ fún Dafidi, iranṣẹ rẹ ṣẹ. +“Ṣugbọn ṣé ìwọ Ọlọrun yóo máa bá eniyan gbé lórí ilẹ̀ ayé? Bí ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́, mélòó mélòó ni ilé tí mo kọ́ yìí? +Sibẹsibẹ, jọ̀wọ́ fetí sí adura ati ẹ̀bẹ̀ èmi iranṣẹ rẹ. OLUWA Ọlọrun mi, gbọ́ igbe èmi iranṣẹ rẹ, ati adura tí mò ń gbà níwájú rẹ. +Ṣugbọn nisinsinyii, mo ti kọ́ ilé kan tí ó lógo fún ọ,ibi tí o óo máa gbé títí lae.” +Máa bojútó ilé yìí tọ̀sán-tòru. O ti sọ pé ibẹ̀ ni àwọn eniyan yóo ti máa jọ́sìn ní orúkọ rẹ. Jọ̀wọ́ máa gbọ́ adura tí èmi iranṣẹ rẹ bá gbà nígbà tí mo bá kọjú sí ilé yìí. +Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ èmi iranṣẹ rẹ, ati ti Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ibí yìí láti gbadura. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa láti ibùgbé rẹ ní ọ̀run, kí o sì dáríjì wá. +“Bí ẹnìkan bá ṣẹ aládùúgbò rẹ̀, tí a sì mú un wá kí ó wá búra níwájú pẹpẹ rẹ ninu ilé yìí, +OLUWA, gbọ́ láti ọ̀run, kí o ṣe ìdájọ́ àwọn iranṣẹ rẹ. Jẹ ẹni tí ó bá ṣẹ̀ níyà bí ó ti tọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí o dá ẹni tí kò ṣẹ̀ láre gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀. +“Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹgun àwọn eniyan rẹ lójú ogun nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ ọ́, ṣugbọn bí wọ́n bá ronupiwada, tí wọ́n ranti orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura, tí wọ́n sì bẹ̀ ọ́ ninu ilé yìí, +jọ̀wọ́ gbọ́ láti ọ̀run, kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, jì wọ́n, kí o sì mú wọn pada sórí ilẹ̀ tí o ti fún àwọn ati àwọn baba wọn. +“Nígbà tí òjò bá kọ̀ tí kò rọ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ ṣẹ̀, bí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé o ti jẹ wọ́n níyà, +jọ̀wọ́, gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dáríjì àwọn eniyan Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ. Tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa tọ̀, kí o sì jẹ́ kí òjò rọ̀ sí ilẹ̀ tí o fún àwọn eniyan rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní wọn. +“Nígbàkúùgbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn bá bẹ́ sílẹ̀, tabi ọ̀gbẹlẹ̀, tabi ìrẹ̀dànù ohun ọ̀gbìn, tabi eṣú, tabi kòkòrò tíí máa jẹ ohun ọ̀gbìn; tabi tí àwọn ọ̀tá bá gbógun ti èyíkéyìí ninu àwọn ìlú wọn, irú ìyọnu tabi àìsàn yòówù tí ó lè jẹ́, +gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan, tabi ti gbogbo Israẹli, eniyan rẹ, lẹ́yìn tí olukuluku ti mọ ìṣòro ati ìbànújẹ́ rẹ̀, bí wọ́n bá gbé ọwọ́ adura wọn sókè sí ìhà ilé yìí, +Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli wà níbẹ̀, ọba bá yíjú pada sí wọn, ó sì gbadura fún wọn. +jọ̀wọ́, gbọ́ láti ilé rẹ ní ọ̀run, dáríjì wọ́n, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ni o mọ ọkàn ọmọ eniyan. +Kí àwọn eniyan rẹ lè máa bẹ̀rù rẹ, kí wọ́n sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wa. +“Bákan náà, nígbà tí àwọn àjèjì, tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, bá ti ọ̀nà jíjìn wá, láti gbadura sí ìhà ilé yìí, nítorí orúkọ ńlá rẹ, ati iṣẹ́ ńlá, ati agbára rẹ, +gbọ́ láti ibùgbé rẹ lọ́run; kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà bá ń tọrọ lọ́dọ̀ rẹ, kí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ, bí àwọn eniyan rẹ tí ń ṣe, kí wọ́n lè mọ̀ pé ilé ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, ni ilé tí mo kọ́ yìí. +“Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá lọ sójú ogun, níbikíbi tí o bá rán wọn, láti lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jà, tí wọ́n bá kọjú sí ìhà ìlú tí o ti yàn yìí ati sí ìhà ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ yìí, +gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì jà fún wọn. +“Bí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ (nítorí pé kò sí ẹni tí kì í ṣẹ̀), tí inú bá bí ọ sí wọn, tí o sì mú kí àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ọ̀nà jíjìn tabi nítòsí, +sibẹ, tí wọ́n bá ranti, tí wọ́n sì ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ tí wọ́n sọ pé, ‘àwọn ti ṣẹ̀, àwọn ti hu ìwà tí kò tọ́, àwọn sì ti ṣe burúkú,’ +tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ninu ìgbèkùn níbi tí a kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n gbadura sí ìhà ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wọn, ati sí ìlú tí o ti yàn, ati sí ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, +gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, jà fún àwọn eniyan rẹ, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ jì wọ́n. +Lẹ́yìn náà, ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó mú ohun gbogbo tí ó wí fún Dafidi, baba mi, ṣẹ fúnrarẹ̀, nítorí ó wí pé, +“Nisinsinyii, Ọlọrun mi, bojúwò wá kí o sì tẹ́tí sí adura tí wọ́n bá gbà níhìn-ín. +Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, dìde, lọ sí ibùjókòó rẹ, ìwọ ati àpótí ẹ̀rí agbára rẹ. Gbé ìgbàlà rẹ wọ àwọn alufaa rẹ bí ẹ̀wù, kí o sì jẹ́ kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ yọ̀ ninu ire rẹ. +Áà! OLUWA Ọlọrun, má ṣe kọ ẹni tí a fi òróró yàn, ranti ìfẹ́ rẹ tí kìí yẹ̀ sí Dafidi, iranṣẹ rẹ.” +‘Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn eniyan jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, n kò tíì yan ìlú kankan ninu ẹ̀yà Israẹli láti kọ́ ilé sí fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi, bẹ́ẹ̀ ni n kò yan ẹnìkan kan láti jẹ́ olórí àwọn eniyan mi. +Ṣugbọn nisinsinyii, mo yan Jerusalẹmu fún ibi ìjọ́sìn ní orúkọ mi, mo sì ti yan Dafidi láti jẹ́ olórí Israẹli, eniyan mi.’ ” +Ó wu Dafidi, baba mi, láti kọ́ ilé kan fún ìjọ́sìn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. +Ṣugbọn OLUWA sọ fún baba mi pé nǹkan dáradára ni pé ó wù ú lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún òun Ọlọrun, +ṣugbọn kì í ṣe òun ni yóo kọ́ ilé náà, ọmọ bíbí inú rẹ̀ ni yóo kọ́ ilé fún òun. +Ọ̀rọ̀ tí Solomoni Bá Àwọn Eniyan Sọ. +Nígbà tí Solomoni parí adura rẹ̀, iná kan ṣẹ́ láti ọ̀run, ó jó gbogbo ẹbọ sísun ati ọrẹ, ògo OLUWA sì kún inú tẹmpili. +Ní ọjọ́ kẹtalelogun oṣù keje, Solomoni ní kí àwọn eniyan máa pada lọ sílé wọn. Inú wọn dùn nítorí ohun rere tí OLUWA ṣe fún Dafidi, ati Solomoni ati gbogbo Israẹli. +Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe parí ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe sí ilé OLUWA ati sí ilé ti ara rẹ̀, ni ó ṣe ní àṣeyọrí. +Lẹ́yìn náà, OLUWA fara han Solomoni lóru, ó ní, “Mo ti gbọ́ adura rẹ, mo sì ti yan ibí yìí ní ilé ìrúbọ fúnra mi. +Nígbà tí mo bá sé ojú ọ̀run, tí òjò kò bá rọ̀, tabi tí mo pàṣẹ fún eṣú láti ba oko jẹ́, tabi tí mo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin àwọn eniyan mi, +bí àwọn eniyan mi, tí à ń fi orúkọ mi pè, bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n bá gbadura, tí wọ́n sì wá ojurere mi, tí wọ́n bá yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú wọnyi; n óo gbọ́ láti ọ̀run, n óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n óo sì wo ilẹ̀ wọn sàn. +Nisinsinyii, n óo fojú sílẹ̀, etí mi yóo sì ṣí sí adura tí wọ́n bá gbà níbí yìí. +Mo ti yan ibí yìí, mo sì ti yà á sí mímọ́, kí á lè máa jọ́sìn ní orúkọ mi níbẹ̀ títí lae. Ojú ati ọkàn mi yóo wà níbẹ̀ nígbà gbogbo. +Ṣugbọn, bí ìwọ bá tẹ̀lé ìlànà mi gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, tí o pa gbogbo òfin mi mọ́, tí o tẹ̀lé ìlànà ati àṣẹ mi, +n óo fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀, bí mo ti bá Dafidi, baba rẹ, dá majẹmu pé, ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí Israẹli. +Ṣugbọn tí o bá yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, tí o kọ àṣẹ mi ati òfin tí mo ṣe fún ọ sílẹ̀, tí o sì ń lọ bọ oriṣa, tí ò ń foríbalẹ̀ fún wọn, +Àwọn alufaa kò sì lè wọ inú tẹmpili lọ mọ́ nítorí ògo OLUWA ti kún ibẹ̀. +n óo fà yín tu kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fun yín bí ẹni fa igi tu. N óo sì kọ tẹmpili yìí, tí mo ti yà sí mímọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi sílẹ̀, nítorí pé yóo di ohun ẹ̀gàn ati àmúpòwe láàrin gbogbo eniyan. +“Tẹmpili yìí gbayì gidigidi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà náà, àwọn ẹni tó bá ń rékọjá lọ yóo máa sọ tìyanu-tìyanu pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí ati sí tẹmpili yìí?’ +Àwọn eniyan yóo dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọ́n kọ OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀, tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n ń lọ bọ oriṣa, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún wọn. Ìdí nìyí tí ibi yìí fi bá wọn.’ ” +Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí i bí iná ati ògo OLUWA ti sọ̀kalẹ̀ sórí tẹmpili, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n sin Ọlọrun, wọ́n fi ọpẹ́ fún un, “Nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé àánú rẹ̀ wà títí lae.” +Lẹ́yìn náà, ọba ati gbogbo àwọn eniyan rúbọ sí OLUWA. +Solomoni ọba fi ẹgbaa mọkanla (22,000) mààlúù ati ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) aguntan rúbọ. Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati gbogbo àwọn eniyan náà ṣe ya il�� Ọlọrun sí mímọ́. +Àwọn alufaa dúró ní ipò wọn, àwọn ọmọ Lefi náà dúró láti kọrin sí OLUWA pẹlu ohun èlò orin tí Dafidi ṣe ati ìlànà tí ó fi lélẹ̀ láti máa fi kọrin ọpẹ́ sí OLUWA pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ wà títí lae;” ní gbogbo ìgbà tí Dafidi bá lò wọ́n láti kọrin ìyìn. Àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè gbogbo eniyan yóo sì dìde dúró. +Solomoni ya gbọ̀ngàn ààrin tí ó wà níwájú ilé OLUWA sí mímọ́, nítorí pé ibẹ̀ ni ó ti rú ẹbọ sísun tí ó sì sun ọ̀rá ẹran fún ẹbọ alaafia, nítorí pé pẹpẹ bàbà tí ó ṣe kò lè gba gbogbo ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ọ̀rá. +Solomoni ṣe àjọyọ̀ yìí fún ọjọ́ meje gbáko, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Israẹli wà pẹlu rẹ̀, eniyan pọ̀ lọ bí eṣú, láti ẹnu bodè Hamati títí dé odò Ijipti. +Wọ́n fi ọjọ́ meje ṣe ìyàsímímọ́ pẹpẹ, wọ́n sì fi ọjọ́ meje ṣe àjọyọ̀. Ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n pe àpéjọ mímọ́. +Yíya Tẹmpili sí Mímọ́. +Ó gba Solomoni ní ogún ọdún láti kọ́ tẹmpili OLUWA ati ààfin tirẹ̀. +Àwọn olórí lára àwọn òṣìṣẹ́ Solomoni jẹ́ igba ati aadọta (250), àwọn ni wọ́n ń ṣe àkóso àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́. +Solomoni mú iyawo rẹ̀, ọmọ Farao kúrò ní ìlú Dafidi, lọ sí ibi tí ó kọ́ fún un. Ó ní, “Iyawo mi kò gbọdọ̀ máa gbé ààfin Dafidi, ọba Israẹli; nítorí pé ibikíbi tí àpótí OLUWA bá ti wọ̀, ó ti di ibi mímọ́.” +Solomoni rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí pẹpẹ OLUWA tí ó kọ́ siwaju yàrá àbáwọlé ní tẹmpili. +Ó ń rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose ti fi lélẹ̀, lojoojumọ, ati ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun ati àwọn àjọ̀dún mẹta pataki tí wọ́n gbọdọ̀ ṣe lọdọọdun: àjọ àìwúkàrà, àjọ ìkórè ati àjọ ìpàgọ́. +Gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dafidi fi lélẹ̀, Solomoni pín àwọn alufaa sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn, ó sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti máa kọ orin ìyìn ati láti máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn alufaa ninu iṣẹ́ wọn ojoojumọ. Ó yan àwọn aṣọ́nà sí oríṣìíríṣìí ẹnu ọ̀nà gẹ́gẹ́ bí Dafidi eniyan Ọlọrun ti pa á láṣẹ. +Wọn kò sì yapa kúrò ninu ìlànà tí Dafidi fi lélẹ̀ fún àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi nípa àwọn ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe, ati nípa ilé ìṣúra. +Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe ṣe gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe láti ìgbà tí ó ti fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀ títí di ìgbà tí ó parí iṣẹ́ náà patapata. +Solomoni lọ sí Esiongeberi ati Elati ní etí òkun ní ilẹ̀ Edomu. +Huramu fi àwọn ọkọ̀ ojú omi ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi ranṣẹ, wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ofiri pẹlu àwọn iranṣẹ Solomoni, wọ́n sì kó ojilenirinwo ati mẹ́wàá (450) ìwọ̀n talẹnti wúrà wá fún Solomoni ọba. +Lẹ́yìn náà, ó tún àwọn ìlú tí Huramu ọba, fún un kọ́, ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli sibẹ. +Ó lọ gbógun ti ìlú Hamati ati Soba, ó sì ṣẹgun wọn. +Ó kọ́ ìlú Tadimori ní aṣálẹ̀, ati gbogbo ìlú tí wọn ń kó ìṣúra jọ sí ní Hamati. +Ó kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati Beti Horoni ti ìsàlẹ̀. Wọ́n jẹ́ ìlú olódi, wọ́n ní ìlẹ̀kùn ati ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn, +bẹ́ẹ̀ sì ni ìlú Baalati ati gbogbo ìlú tí wọn ń kó ìṣúra pamọ́ sí, ati àwọn ìlú tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ wà, ati ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin, ati gbogbo ohun tí ó pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ati ní Lẹbanoni, ati ní gbogbo ibi tí ìjọba rẹ̀ dé. +Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ilẹ̀ náà lára àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Amori, àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, tí wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli, +gbogbo ìran àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò parun, ni Solomoni ń fi tipátipá kó ṣiṣẹ́ títí di òní olónìí. +Ṣugbọn kò fi ipá kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ bí ẹrú, ṣugbọn ó ń lò wọ́n bíi jagunjagun, òṣìṣẹ́ ìjọba, balogun kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. +Àwọn Àsẹyọrí Solomoni. +Nígbà tí ọbabinrin ìlú Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó wá sí Jerusalẹmu láti wá dán an wò pẹlu àwọn ìbéèrè tó le. Ó wá ninu ọlá ńlá rẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan ni wọ́n tẹ̀lé e lẹ́yìn, pẹlu àwọn ràkúnmí tí wọ́n ru oríṣìírìṣìí turari olóòórùn dídùn, ati ọpọlọpọ wúrà ati òkúta olówó iyebíye. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ fún un. +Àwọn iranṣẹ Huramu ati àwọn iranṣẹ Solomoni tí wọ́n mú wúrà wá láti Ofiri, tún mú igi aligumu ati àwọn òkúta olówó iyebíye wá pẹlu. +Igi aligumu yìí ni ọba fi ṣe àtẹ̀gùn láti máa gòkè ati láti máa sọ̀kalẹ̀ ninu tẹmpili OLUWA ati ninu ààfin ọba. Ó tún fi ṣe dùùrù ati hapu fún àwọn akọrin. Kò sí irú wọn rí ní gbogbo ilẹ̀ Juda. +Solomoni ọba fún ọbabinrin náà ní gbogbo ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ẹ̀bùn tí ó fún un ju èyí tí òun alára mú wá lọ. Lẹ́yìn náà ọbabinrin náà pada lọ sí ìlú rẹ̀. +Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni ń rí ní ọdọọdún jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó lé mẹfa (666) talẹnti (kilogiramu 23,000), +láìka èyí tí àwọn oníṣòwò ati àwọn ọlọ́jà ń mú wá. Àwọn ọba Arabia ati àwọn gomina àwọn agbègbè ìjọba rẹ̀ náà a máa mú wúrà ati fadaka wá fún un. +Solomoni fi wúrà tí a fi òòlù lù ṣe igba (200) apata ńláńlá. Ìwọ̀n wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹta (600) ṣekeli. +Ó tún fi wúrà tí a fi òòlù lù ṣe ọọdunrun (300) apata kéékèèké. Ìwọ̀n wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọọdunrun (300) ṣekeli. Ọba kó wọn sí ààfin Igbó Lẹbanoni. +Ọba fi eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan, ó sì yọ́ ojúlówó wúrà bò ó. +Ìtẹ́ náà ní àtẹ̀gùn kan tí ó ní ìṣísẹ̀ mẹfa ati àpótí ìtìsẹ̀ kan tí a fi wúrà ṣe, tí a kàn mọ́ ìtẹ́. Igbọwọle wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ìtẹ́ náà, tí ère kinniun meji wà ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn. +Wọ́n ṣe ère kinniun mejila sí ẹ̀gbẹ́ àtẹ̀gùn náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìṣísẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Kò sí irú rẹ̀ rí ní ìjọba kankan. +Solomoni dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀. Kò sí ẹyọ kan tí ó rú Solomoni lójú, tí kò dáhùn pẹlu àlàyé. +Wúrà ni wọ́n fi ṣe gbogbo ife Solomoni, ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Igbó Lẹbanoni. Fadaka kò jámọ́ nǹkankan ní àkókò ìjọba Solomoni. +Nítorí pé, ọba ní àwọn ọkọ̀ ojú omi tí àwọn iranṣẹ Huramu máa ń gbé lọ sí Taṣiṣi. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún mẹta ni àwọn ọkọ̀ náà máa ń dé; wọn á máa kó wúrà, fadaka, eyín erin, ati oríṣìíríṣìí àwọn ọ̀bọ ati ẹyẹ ọ̀kín wá sílé. +Solomoni ọba ní ọrọ̀ ati ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba yòókù lọ lórí ilẹ̀ ayé. +Gbogbo wọn ni wọ́n ń wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí Ọlọrun fún un. Fún ọpọlọpọ ọdún ni +ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn máa ń mú ẹ̀bùn wá fún un lọdọọdun, àwọn ẹ̀bùn bíi: ohun èlò fadaka, ati ti wúrà, aṣọ, ohun ìjà ogun, turari, ẹṣin, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. +Solomoni ọba ní ẹgbaaji (4,000) ilé fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, ó ní ẹgbaafa (12,000) ẹlẹ́ṣin. Ó kó àwọn kan sí àwọn ìlú tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sí, ó kó ìyókù sí Jerusalẹmu, níbi tí ọba ń gbé. +Solomoni jọba lórí àwọn ọba gbogbo, láti odò Yufurate títí dé ilẹ̀ àwọn ará Filistia ati títí dé ààlà Ijipti. +Ní àkókò tirẹ̀, ó mú kí fadaka pọ̀ bí òkúta ní Jerusalẹmu, igi kedari sì pọ̀ bíi igi sikamore tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè Juda. +A máa ra ẹṣin wá láti Ijipti ati láti gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù. +Gbogbo ìtàn ìjọba Solomoni, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, wà ninu ìwé ìtàn wolii Natani, ati ninu ìwé àsọtẹ́lẹ̀ Ahija ará Ṣilo, ati ninu ìwé ìran tí Ido rí nípa Jeroboamu ọba Israẹli, ọmọ Nebati. +Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba rí i bí ọgbọ́n Solomoni ti jinlẹ̀ tó, ati ààfin tí ó kọ́, +Solomoni jọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo Israẹli fún ogoji ọdún. +Ó kú, a sì sin ín sí ìlú Dafidi, baba rẹ̀. Rehoboamu, ọmọ rẹ̀, ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀. +oúnjẹ tí ó wà lórí tabili rẹ̀ ati bí àwọn ìjòyè rẹ̀ ti jókòó, àwọn iranṣẹ rẹ̀, ìwọṣọ ati ìṣesí wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀ ati ìwọṣọ wọn, ati ẹbọ sísun tí ó ń rú ní ilé OLUWA, ẹnu yà á lọpọlọpọ. +Ó sọ fún Solomoni ọba pé, “Kò sí irọ́ ninu gbogbo ohun tí mo ti gbọ́ nípa rẹ ati nípa ọgbọ́n rẹ. +N kò gba ohun tí wọ́n sọ fún mi gbọ́ títí tí mo fi dé ìhín, tí èmi gan-an sì fi ojú ara mi rí i. Ohun tí wọ́n sọ fún mi kò tó ìdajì ọgbọ́n rẹ, ohun tí mo rí yìí pọ̀ ju ohun tí wọ́n sọ fún mi lọ. +Àwọn iyawo rẹ ṣoríire. Àwọn òṣìṣẹ́ rẹ tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n rẹ náà ṣoríire. +Ògo ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ, tí inú rẹ̀ dùn sí ọ, tí ó gbé ọ gorí oyè láti jọba ní orúkọ rẹ̀. Ó ní ìfẹ́ sí Israẹli, ó fẹ́ fi ìdí wọn múlẹ̀ títí lae; nítorí náà, ó fi ọ́ jọba lórí wọn, láti máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo.” +Ó fún ọba ní àwọn ẹ̀bùn wọnyi tí ó mú wá: ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà, ọpọlọpọ turari olóòórùn dídùn ati ohun ọ̀ṣọ́ òkúta olówó iyebíye. Kò tún sí irú turari tí ọbabinrin yìí mú wá fún Solomoni ọba mọ́. +Ìbẹ̀wò Ọbabinrin Ṣeba sí Solomoni. +Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọrun, ati Timoti, arakunrin wa, ni à ń kọ ìwé yìí sí Ìjọ Ọlọrun tí ó wà ní Kọrinti ati sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Akaya. +Ọlọrun ni ó yọ wá ninu ewu ńlá náà, òun ni yóo sì máa yọ wá. Òun ni a ní ìrètí ninu rẹ̀; yóo sì tún máa yọ wá, +bí ẹ bá ń fi adura yín ràn wá lọ́wọ́. Nígbà náà ni ọpọlọpọ eniyan yóo ṣọpẹ́ nítorí ọpọlọpọ oore tí Ọlọrun ṣe fún wa. +Nǹkankan wà tí a lè fi ṣe ìgbéraga, ẹ̀rí-ọkàn wa sì jẹ́rìí sí i pé pẹlu ọkàn kan ati inú kan níwájú Ọlọrun ni a fi ń bá gbogbo eniyan lò, pàápàá jùlọ ẹ̀yin gan-an. Kì í ṣe ọgbọ́n eniyan bíkòṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. +Kò sí ohunkohun tí a kọ si yín tí ẹ kò lè kà kí ó ye yín. Mo sì ní ìrètí pé yóo ye yín jálẹ̀. +Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ẹ kò ì tíì mọ̀ wá dáradára, ẹ óo rí i pé a óo jẹ́ ohun ìṣògo fun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà yóo ti jẹ́ fún wa ní ọjọ́ tí Oluwa wa, Jesu, bá dé. +Nítorí ó dá mi lójú bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe fẹ́ kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ yín, kí ayọ̀ yín lè di ìlọ́po meji. +Ǹ bá gba ọ̀dọ̀ yín lọ sí Masedonia, ǹ bá sì tún gba ọ̀dọ̀ yín lábọ̀. Ǹ bá wá ṣe ètò láti wá ìrànlọ́wọ́ fún ìrìn àjò mi sí Judia. +Ohun tí mo ní lọ́kàn nìyí. Ǹjẹ́ kò ní ìdí tí mo fi yí ètò yìí pada? Àbí ẹ rò pé nígbà tí mò ń ṣe ètò, mò ń ṣe é bí ẹni tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni, tí ó fi jẹ́ pé ẹnu kan náà tí mo fi pe “bẹ́ẹ̀ ni” ni n óo tún fi pe “bẹ́ẹ̀ kọ́?” +Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, ọ̀rọ̀ wa pẹlu yín ti kúrò ní “bẹ́ẹ̀ ni” ati “bẹ́ẹ̀ kọ́.” +Nítorí Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, tí èmi, Silifanu ati Timoti, ń waasu rẹ̀ fun yín, kì í ṣe “bẹ́ẹ̀ ni” ati “bẹ́ẹ̀ kọ́”. Ṣugbọn “bẹ́ẹ̀ ni” ni tirẹ̀. +Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín. +Nítorí gbogbo ìlérí Ọlọrun di “bẹ́ẹ̀ ni” ninu rẹ̀. Ìdí tí a fi ń ṣe “Amin” ní orúkọ rẹ̀ nìyí, nígbà tí a bá ń fi ògo fún Ọlọrun. +Ọlọrun ni ó fún àwa ati ẹ̀yin ní ìdánilójú pé a wà ninu Kristi, òun ni ó ti fi òróró yàn wá. +Ó ti fi èdìdì rẹ̀ sí wa lára, ó tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe onídùúró sí ọkàn wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí yóo tún fún wa. +Mo fi Ọlọrun jẹ́rìí ohun tí n óo sọ yìí. Mo sì fi ẹ̀mí mi búra! Ìdí tí n kò fi wá sí Kọrinti mọ́ ni pé n kò fẹ́ yọ yín lẹ́nu. +Kì í ṣe pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ fi agbára ti igbagbọ bọ̀ yín lọ́rùn ni, nítorí ẹ ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu igbagbọ. Ṣugbọn a jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹlu yín ni, kí ẹ lè ní ayọ̀. +A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba aláàánú ati Ọlọrun orísun ìtùnú, +ẹni tí ó ń fún wa ní ìwúrí ninu gbogbo ìpọ́njú tí à ń rí, kí àwa náà lè fi ìwúrí fún àwọn tí ó wà ninu oríṣìíríṣìí ìpọ́njú nípa ìwúrí tí àwa fúnra wa ti níláti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. +Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti ní ìpín ninu ọpọlọpọ ìyà Kristi, bẹ́ẹ̀ náà ni a ní ọpọlọpọ ìwúrí nípasẹ̀ Kristi. +Ṣugbọn bí a bá wà ninu ìpọ́njú, fún ìwúrí ati ìgbàlà yín ni. Bí a bá ní ìwúrí, ẹ̀yin náà yóo ní ìwúrí; ìwúrí yìí yóo sì kọ yín ní sùúrù nígbà tí ẹ bá ń jẹ irú ìyà tí àwa náà ń jẹ. +Ìrètí wa lórí yín sì ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, nítorí tí a mọ̀ pé bí a ti jọ ń jẹ irú ìyà kan náà, bẹ́ẹ̀ náà ni a jọ ní irú ìwúrí kan náà. +Ẹ̀yin ará, a kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa ìpọ́njú tí ó tayọ agbára wa tí a ní ní Esia, Ìdààmú náà wọ̀ wá lọ́rùn tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀mí wa fi fẹ́rẹ̀ bọ́. +A ṣe bí wọ́n tí dá wa lẹ́bi ikú ni. Kí á má baà gbẹ́kẹ̀lé ara wa, bíkòṣe Ọlọrun, ni ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Nítorí Ọlọrun níí jí òkú dìde. +Ìkíni. +Èmi Paulu fi ìrẹ̀lẹ̀ Kristi ati àánú rẹ̀ bẹ̀ yín, èmi tí ẹ̀ ń sọ pé nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín mo jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ṣugbọn nígbà tí mo bá kúrò lọ́dọ̀ yín mo di ògbójú si yín. +Nítorí àwọn kan ń sọ pé, “Àwọn ìwé tí Paulu kọ jinlẹ̀, wọ́n sì le, ṣugbọn bí ẹ bá rí òun alára, bí ọlọ́kùnrùn ni ó rí, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ta eniyan lára.” +Kí ẹni tí ó bá ń rò báyìí mọ̀ pé bí a ti jẹ́ ninu ọ̀rọ̀ tí a kọ sinu ìwé nígbà tí a kò sí lọ́dọ̀ yín, bẹ́ẹ̀ náà ni a jẹ́ ninu iṣẹ́ wa nígbà tí a bá wà lọ́dọ̀ yín. +Nítorí a kò gbọdọ̀ da ara wa mọ́ àwọn kan tí wọn ń yin ara wọn, tabi kí á fara wé wọn. Fúnra wọn ni wọ́n ṣe òṣùnwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn ara wọn, àwọn tìkalára wọn náà ni wọ́n sì ń fi ara wọn wé. Wọn kò lóye. +Ṣugbọn ní tiwa, a kò ní lérí ju bí ó ti yẹ lọ. Òṣùnwọ̀n wa kò tayọ ààlà tí Ọlọrun ti pa sílẹ̀ fún wa, tí a fi mú ìyìn rere dé ọ̀dọ̀ yín. +Nítorí kì í ṣe pé a kọjá àyè wa nígbà tí a dé ọ̀dọ̀ yín, àwa ni a sì kọ́kọ́ mú ìyìn rere Kristi dé ọ̀dọ̀ yín. +A kò gbọdọ̀ ṣe ìgbéraga pupọ ju bí ó ti yẹ lọ lórí iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn. A ní ìrètí pé bí igbagbọ yín ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ipò wa pẹlu yín yóo máa ga sí i, gẹ́gẹ́ bí ààyè wa. +A óo wá mú ọ̀rọ̀ ìyìn rere kọjá ọ̀dọ̀ yín, láì ṣe ìgbéraga nípa iṣẹ́ tí ẹlòmíràn ti ṣe ní ààyè tirẹ̀. +Ṣugbọn ẹni tí yóo bá ṣe ìgbéraga, Oluwa ni kí ó fi ṣe ìgbéraga. +Kì í ṣe ẹni tí ó yin ara rẹ̀ ni ó yege, bíkòṣe ẹni tí Oluwa bá yìn. +Mo bẹ̀ yín, ẹ má ṣe jẹ́ kí n wá sọ́dọ̀ yín pẹlu ìgbójú, nítorí ó dá mi lójú pé mo lè ko àwọn kan, tí wọ́n sọ pé à ń hùwà bí ẹni tí ó ń wá ire ara wa lójú. +Nítorí à ń gbé ìgbé-ayé wa ninu àìlera ti ara, ṣugbọn a kò jagun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń wá ire ara wa, +nítorí àwọn ohun-ìjà wa kì í ṣe ti ayé, agbára Ọlọrun ni, tí a lè fi wó ìlú olódi. À ń bi gbogbo iyàn jíjà lórí èké ṣubú, +ati gbogbo ìdínà tí ó bá gbórí sókè tí ó lòdì sí ìmọ̀ Ọlọrun. A mú gbogbo èrò ọkàn ní ìgbèkùn kí ó lè gbọ́ràn sí Kristi lẹ́nu. +A sì ti múra tán láti jẹ gbogbo aláìgbọràn níyà, nígbà tí ẹ bá ti fi ara yín sábẹ́ wa. +Nǹkan ti òde ara nìkan ni ẹ̀ ń wò! Bí ẹnikẹ́ni bá dá ara rẹ̀ lójú pé òun jẹ́ ti Kristi, kí ó tún inú ara rẹ̀ rò wò, nítorí bí ó ti jẹ́ ti Kristi, bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwa náà jẹ́. +Nítorí ojú kò tì mí bí mo bá ń ṣe ìgbéraga ní àṣejù nípa àṣẹ tí a ní, tí Oluwa fi fún mi, láti lè mu yín dàgbà ni, kì í ṣe láti fi bì yín ṣubú. +N kò fẹ́ kí ẹ rò pé mò ń fi àwọn ìwé tí mò ń kọ dẹ́rù bà yín. +Paulu Gbèjà Ara Rẹ̀. +Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbà mí láyè kí n sọ̀rọ̀ díẹ̀ bí aṣiwèrè. Ẹ gbà mí láyè. +Gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ Kristi ti wà ninu mi, kò sí ohun tí yóo mú mi yipada ninu ohun tí mo fi ń ṣe ìgbéraga ní gbogbo agbègbè Akaya. +Nítorí kí ni? A máa ṣe pé n kò fẹ́ràn yín ni? Ọlọrun mọ̀ pé mo fẹ́ràn yín. +Bí mo ti ń ṣe ni n óo tún máa ṣe, kí n má baà fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe ìgbéraga pé iṣẹ́ wọn dàbí tiwa. +Aposteli èké ni irú àwọn bẹ́ẹ̀. Ẹlẹ́tàn ni wọ́n, tí wọn ń farahàn bí aposteli Kristi. +Irú rẹ̀ kì í ṣe nǹkan ìjọjú, nítorí Satani pàápàá a máa farahàn bí angẹli ìmọ́lẹ̀. +Nítorí náà, kò ṣòro fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ láti farahàn bí iranṣẹ tòótọ́. Ṣugbọn ìgbẹ̀yìn wọn yóo rí bí iṣẹ́ wọn. +Mo tún wí lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé aṣiwèrè ni mí. Ṣugbọn bí ẹ bá rò bẹ́ẹ̀, ẹ sá gbà mí bí aṣiwèrè, kí n lè fọ́nnu díẹ̀. +N kò sọ̀rọ̀ bí onigbagbọ nípa ohun tí mo fi ń fọ́nnu yìí, bí aṣiwèrè ni mò ń sọ̀rọ̀. +Ọpọlọpọ ní ń fọ́nnu nípa nǹkan ti ara, ẹ jẹ́ kí èmi náà fọ́nnu díẹ̀! +Pẹlu ayọ̀ ni ẹ fi ń gba àwọn aṣiwèrè, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n! +Mò ń jowú nítorí yín, bí Ọlọrun tií jowú. Nítorí èmi ni mo ṣe ètò láti fà yín fún Kristi bí ẹni fa wundia tí ó pé fún ọkọ rẹ̀. +Bí ẹnìkan bá ń lò yín bí ẹrú, tí ó ń jẹ yín run, tí ó fi okùn mu yín, tí ó ń ṣe fùkẹ̀ láàrin yín, tí ó ń gba yín létí, ẹ ṣetán láti gba irú ẹni bẹ́ẹ̀. +Ojú tì mí láti gbà pé àwa kò lágbára tó láti hu irú ìwà bẹ́ẹ̀!Ṣugbọn bí ẹnìkan bá láyà láti fi ohun kan ṣe ìgbéraga, ẹ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ bí aṣiwèrè, èmi náà láyà láti ṣe ìgbéraga. +Ṣé Heberu ni wọ́n ni? Heberu ni èmi náà. Ọmọ Israẹli ni wọ́n? Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà. Ṣé ìdílé Abrahamu ni wọ́n? Òun ni èmi náà. +Iranṣẹ Kristi ni wọ́n? Tí n óo bá sọ̀rọ̀ bí ẹni tí orí rẹ̀ kò pé, mo jù wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Kristi. Mo ti fi agbára ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ. Mo ti wẹ̀wọ̀n nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Wọ́n ti nà mí nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Ẹ̀mí fẹ́rẹ̀ bọ́ lẹ́nu mi ní ọpọlọpọ ìgbà. +Ẹẹmarun-un ni àwọn Juu nà mí ní ẹgba mọkandinlogoji. +Ẹẹmẹta ni a fi ọ̀pá lù mí. A sọ mí lókùúta lẹ́ẹ̀kan. Ẹẹmẹta ni ọkọ̀ ojú omi tí mo wọ̀ rì. Fún odidi ọjọ́ kan, tọ̀sán-tòru, ni mo fi wà ninu agbami. +Ní ọpọlọpọ ìgbà ni mo wà lórí ìrìn àjò, tí mo wà ninu ewu omi, ewu lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, ewu láàrin àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ mi, ewu láàrin àwọn tíí ṣe Juu, ewu ninu ìlú, ewu ninu oko, ewu lójú òkun, ati ewu láàrin àwọn èké onigbagbọ. +Mo ti rí ọ̀pọ̀ wahala ati ìṣòro. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni n kò lè sùn. Ebi pa mí, òùngbẹ gbẹ mí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mò ń gbààwẹ̀. Mo mọ ìgbà òtútù ati ìgbà tí aṣọ kò tó láti fi bora. +Láì ka àwọn nǹkan mìíràn tí n kò mẹ́nubà, lojoojumọ ni àníyàn gbogbo àwọn ìjọ wúwo lọ́kàn mi. +Ta ni jẹ́ aláìlera tí n kò ní ìpín ninu àìlera rẹ̀? Ta ni ṣubú sinu ẹ̀ṣẹ̀ tí ọkàn mi kò bàjẹ́? +Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ẹ̀tàn má wọ inú ọkàn yín, tí ẹ óo fi yà kúrò ninu òtítọ́ ati ọkàn kan tí ẹ fi wà ninu Kristi, bí ejò ti fi àrékérekè rẹ̀ tan Efa jẹ. +Bí mo bá níláti fọ́nnu, n óo fọ́nnu nípa àwọn àìlera mi. +Ọlọrun Baba Oluwa wa Jesu, ẹni tí ìyìn yẹ fún títí lae, mọ̀ pé n kò purọ́. +Ní Damasku, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ Ọba Areta ń ṣọ́ ẹnu odi ìlú láti mú mi. +Apẹ̀rẹ̀ ni wọ́n fi sọ̀ mí kalẹ̀ láti ojú fèrèsé lára odi ìlú, ni mo fi bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. +Nítorí ẹ̀ ń fi ààyè gba àwọn ẹlòmíràn tí wọn ń wá waasu Jesu yàtọ̀ sí bí a ti waasu rẹ̀, ẹ sì ń gba ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti kọ́ gbà. +N kò rò pé mo kéré sí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní “aposteli” pataki wọnyi! +Ọ̀rọ̀ lè má dùn lẹ́nu mi, ṣugbọn mo ní ìmọ̀, ní ọ̀nà gbogbo a ti mú kí èyí hàn si yín ninu ohun gbogbo. +Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni mo ṣẹ̀ tí mo fi ara mi sí ipò ìrẹ̀lẹ̀, kí ẹ lè ní ipò gíga? Àbí ẹ̀ṣẹ̀ ni, pé mo waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín láì gba nǹkankan lọ́wọ́ yín? +Mo fẹ́rẹ̀ jẹ àwọn ìjọ mìíràn run, tí mò ń gba owó lọ́wọ́ wọn láti ṣe iṣẹ́ fun yín. +Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín, tí mo ṣe aláìní, n kò ni ẹnikẹ́ni lára, àwọn arakunrin tí ó wá láti Masedonia ni wọ́n mójútó àwọn ohun tí mo ṣe aláìní. Ninu gbogbo nǹkan, mo ṣe é lófin pé n kò ní wọ̀ yín lọ́rùn, n kò sì ní yí òfin yìí pada! +Paulu ati Àwọn Aposteli Èké. +Ó yẹ kí n fọ́nnu. Rere kan kò ti ibẹ̀ wá, sibẹ n óo sọ ti ìran ati ìfarahàn Oluwa. +Nítorí èyí mo ní inú dídùn ninu àìlera mi, ati ninu àwọn ìwọ̀sí, ìṣòro, inúnibíni ati ìpọ́njú tí mo ti rí nítorí ti Kristi. Nítorí nígbà tì mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára. +Mo ti di aṣiwèrè! Ẹ̀yin ni ẹ sì sọ mí dà bẹ́ẹ̀. Nítorí ìyìn ni ó yẹ kí n gbà lọ́dọ̀ yín. Nítorí bí n kò tilẹ̀ jẹ́ nǹkankan, n kò rẹ̀yìn ninu ohunkohun sí àwọn aposteli yín tí ẹ kà kún pataki. +Àwọn àmì aposteli hàn ninu iṣẹ́ mi láàrin yín nípa oríṣìíríṣìí ìfaradà, nípa iṣẹ́ abàmì, iṣẹ́ ìyanu, ati iṣẹ́ agbára. +Ọ̀nà wo ni a fi ba yín lò tí ó burú ju ti àwọn ìjọ ìyókù lọ; àfi ti pé èmi fúnra mi kò ni yín lára? Ẹ forí jì mí fún àṣìṣe yìí! +Ẹ wò ó! Ẹẹkẹta nìyí tí mo múra tán láti wá sọ́dọ̀ yín. N kò sì ní ni yín lára. Nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan dúkìá yín ni mo fẹ́ bíkòṣe ẹ̀yin fúnra yín. Nítorí kì í ṣe àwọn ọmọ ni ó yẹ láti pèsè fún àwọn òbí wọn. Àwọn òbí ni ó yẹ kí ó pèsè fún àwọn ọmọ. +Ní tèmi, pẹlu ayọ̀ ni ǹ bá fi náwó-nára patapata fún ire ọkàn yín. Bí èmi bá fẹ́ràn yín pupọ, ṣé díẹ̀ ni ó yẹ kí ẹ̀yin fẹ́ràn mi? +Ẹ gbà pé n kò ni yín lára. Ṣugbọn àwọn kan rò pé ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ni mí, ati pé ẹ̀tàn ni mo fi mu yín. +Ninu àwọn tí mo rán si yín, èwo ni mo lò láti fi rẹ yín jẹ? +Mo bẹ Titu kí ó wá sọ́dọ̀ yín. Mo tún rán arakunrin wa pẹlu rẹ̀. Ǹjẹ́ Titu rẹ yín jẹ bí? Ṣebí Ẹ̀mí kan náà ni ó ń darí wa? Tabi kì í ṣe ọ̀nà kan náà ni a jọ ń ṣiṣẹ́? +Ṣé ohun tí ẹ ti ń rò ni pé à ń wí àwíjàre níwájú yín? Rárá o! Níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ ni à ń sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, gbogbo nǹkan tí à ń ṣe, fún ìdàgbàsókè yín ni. +Mo mọ ọkunrin onigbagbọ kan ní ọdún mẹrinla sẹ́yìn. Bí ó wà ninu ara ni o, bí ó rí ìran ni o, èmi kò mọ̀–Ọlọrun ni ó mọ̀. A gbé ọkunrin yìí lọ sí ọ̀run kẹta. +Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà ti mo bá dé, mo lè má ba yín ní irú ipò tí mo fẹ́, ati pé ẹ̀yin náà lè rí i pé n kò rí bí ẹ ti ń rò. Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ohun tí n óo bá láàrin yín má jẹ́ ìjà ati owú jíjẹ, ibinu ati ìwà ọ̀kánjúwà, ọ̀rọ̀ burúkú ati ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga ati ìrúkèrúdò. +Ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà tí mo bá tún dé, kí Ọlọrun mi má dójú tì mí níwájú yín, kí n má ní ìbànújẹ́ nítorí ọpọlọpọ tí wọ́n ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ tí wọn kò ronupiwada kúrò ninu ìṣekúṣe, àgbèrè ati ìwà wọ̀bìà tí wọ́n ti ń hù. +Mo mọ ọkunrin yìí, bí ninu ara ni o, bí lójú ìran ni o, èmi kò mọ̀–Ọlọrun ni ó mọ̀. A gbé e lọ sí Paradise níbi tí ó gbé gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣe é sọ, ọ̀rọ̀ àṣírí tí kò gbọdọ̀ jáde lẹ́nu eniyan. +N óo fọ́nnu nípa irú ọkunrin bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ní fọ́nnu nípa ara tèmi ati nípa àwọn àìlera mi. +Bí mo bá fẹ́ fọ́nnu, kò ní jẹ́ ọ̀rọ̀ aṣiwèrè ni n óo sọ; òtítọ́ ni n óo sọ. Ṣugbọn n kò ní ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má baà rò nípa mi ju ohun tí ó rí ninu ìwà mi ati ohun tí ó gbọ́ lẹ́nu mi lọ. +Nítorí náà, kí n má baà ṣe ìgbéraga nípa àwọn ìfihàn tí ó ga pupọ wọnyi, a fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ẹ̀gún yìí jẹ́ iranṣẹ Satani, láti máa gún mi, kí n má baà gbéraga. +Ẹẹmẹta ni mo bẹ Oluwa nítorí rẹ̀ pé kí ó mú un kúrò lára mi. +Ìdáhùn tí ó fún mi ni pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ. Ninu àìlera rẹ ni agbára mi di pípé.” Nítorí náà ninu àwọn ohun tí ó jẹ́ àìlera fún mi ni mo ní ayọ̀ pupọ jùlọ, àwọn ni n óo fi ṣe ìgbéraga, kí agbára Kristi lè máa bá mi gbé. +Àwọn Ìran Tí Paulu Rí. +Ẹẹkẹta nìyí tí n óo wá sọ́dọ̀ yín. Lẹ́nu ẹlẹ́rìí meji tabi mẹta ni a óo sì ti mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀. +Ìdí tí mo fi ń kọ gbogbo nǹkan wọnyi nígbà tí n kò sí lọ́dọ̀ yín ni pé nígbà tí mo bá dé, kí n má baà fi ìkanra lo àṣẹ tí Oluwa ti fi fún mi láti fi mú ìdàgbà wá, kì í ṣe láti fi wo yín lulẹ̀. +Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ó dìgbà! Ẹ tún ọ̀nà yín ṣe. Ẹ gba ìkìlọ̀ wa. Ẹ ní ọkàn kan náà láàrin ara yín. Ẹ máa gbé pọ̀ ní alaafia. Ọlọrun ìfẹ́ ati alaafia yóo wà pẹlu yín. +Ẹ fi ìfẹnukonu ti alaafia kí ara yín. Gbogbo àwọn onigbagbọ ki yín. +Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa Jesu Kristi, ati ìfẹ́ Ọlọrun ati ìdàpọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ wà pẹlu gbogbo yín. +Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ fún àwọn tí wọ́n ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ ati àwọn yòókù, tí mo tún sọ nígbà tí mo wá sọ́dọ̀ yín lẹẹkeji, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń sọ nisinsinyii tí n kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá tún dé, n kò ní ṣojú àánú; +nígbà tí ó ti jẹ́ pé ẹ̀rí ni ẹ̀ ń wá pé Kristi ń lò mí láti sọ̀rọ̀. Kristi kì í ṣe aláìlera ninu ìbálò rẹ̀ pẹlu yín. +Òtítọ́ ni pé a kàn án mọ́ agbelebu ní àìlera, ṣugbọn ó wà láàyè nípa agbára Ọlọrun. Òtítọ́ ni pé àwa náà jẹ́ aláìlera pẹlu rẹ̀, ṣugbọn a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀ nípa agbára Ọlọrun ninu ìbálò wa pẹlu yín. +Ẹ yẹ ara yín wò bí ẹ bá ń gbé ìgbé-ayé ti igbagbọ. Ẹ yẹ ara yín wò. Àbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ̀ pé Kristi Jesu wà ninu yín? Àfi bí ẹ bá ti kùnà nígbà tí ẹ yẹ ara yín wò! +Ṣugbọn mo ní ìrètí pé ẹ mọ̀ pé ní tiwa, àwa kò kùnà. +À ń gbadura sí Ọlọrun pé kí ẹ má ṣe nǹkan burúkú kan, kì í ṣe pé nítorí kí á lè farahàn bí ẹni tí kò kùnà, ṣugbọn kí ẹ̀yin lè máa ṣe rere, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa dàbí ẹni tí ó kùnà. +Nítorí a kò lè ṣe nǹkankan tí ó lòdì sí òtítọ́, àfi òtítọ́. +Nítorí náà inú wa dùn nígbà tí àwa bá jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára. Èyí ni à ń gbadura fún, pé kí ẹ tún ìgbé-ayé yín ṣe. +Ìkìlọ̀ Ìgbẹ̀yìn. +Nítorí náà, mo pinnu pé n kò tún fẹ́ kí wíwá tí mo bá wá sọ́dọ̀ yín jẹ́ ti ìbànújẹ́ mọ́. +Bí ẹ bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi náà dáríjì í. Nítorí tí mo bá ti dáríjì eniyan, (bí nǹkankan bá fi ìgbà kan wà tí mo fi níláti dáríjì ẹnikẹ́ni), mo ṣe é nítorí tiyín níwájú Kristi. +Nítorí a kò gbọdọ̀ gba Èṣù láyè láti lò wá, nítorí a kò ṣàì mọ ète rẹ̀. +Nígbà tí mo dé Tiroasi láti waasu ìyìn rere Kristi, Oluwa ṣínà fún mi láti ṣiṣẹ́. +Ṣugbọn ọkàn mi kò balẹ̀ nígbà tí n kò rí Titu arakunrin mi níbẹ̀. Mo bá dágbére fún àwọn eniyan níbẹ̀, mo lọ sí Masedonia. +Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó jẹ́ kí á lè wà ninu àjọyọ̀ ìṣẹ́gun tí Kristi ṣẹgun, nígbà gbogbo. Ọlọrun náà ni ó tún ń mú kí ìmọ̀ rẹ̀ tí ń jáde láti ara wa máa gba gbogbo ilẹ̀ káàkiri bí òórùn dídùn níbi gbogbo. +Nítorí àwa ni òórùn dídùn tí Kristi fi rúbọ sí Ọlọrun lọ́dọ̀ àwọn tí à ń gbàlà ati àwọn tí ń ṣègbé. +Fún àwọn tí wọn ń ṣègbé, a dàbí òórùn tí n pani, ṣugbọn fún àwọn tí à ń gbàlà, a dàbí òórùn dídùn tí ó ń fún wọn ní ìyè. Ta ló tó ṣe irú iṣẹ́ yìí? +Nítorí àwa kì í ṣe àwọn tí ń ba ọ̀rọ̀ Ọlọrun jẹ́ nítorí èrè tí wọn óo rí jẹ níbẹ̀, bí ọpọlọpọ tí ń ṣe. Ṣugbọn à ń waasu pẹlu ọkàn kan bí eniyan Kristi, ati gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọrun rán níṣẹ́, tí ó ń ṣiṣẹ́ níwájú Ọlọrun. +Bí mo bá bà yín ninu jẹ́, ta ni yóo mú inú mi dùn bí kò bá ṣe ẹ̀yin kan náà tí mo bà ninu jẹ́? +Ìdí tí mo fi kọ ìwé tí mo kọ si yín nìyí, nítorí n kò fẹ́ wá kí n tún ní ìbànújẹ́ láti ọ̀dọ̀ ẹ̀yin tí ó yẹ kí ẹ fún mi láyọ̀. Ó dá mi lójú pé bí mo bá ń yọ̀, inú gbogbo yín ni yóo máa dùn. +Nítorí pẹlu ọpọlọpọ ìdààmú ati ọkàn wúwo ni mo fi kọ ọ́, kì í ṣe pé kí ó lè bà yín lọ́kàn jẹ́ ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé ìfẹ́ tí mo ní si yín pọ̀ pupọ. +Ní ti ẹni tí ó dá ìbànújẹ́ yìí sílẹ̀, èmi kọ́ ni ó bà ninu jẹ́ rárá. Láì tan ọ̀rọ̀ náà lọ títí, bí ó ti wù kí ó mọ, gbogbo yín ni ó bà ninu jẹ́. +Ìyà tí ọpọlọpọ ninu yín ti fi jẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti tó. +Kí ẹ wá dáríjì í. Kí ẹ fún un ní ìwúrí. Bí ìbànújẹ́ bá tún pọ̀ lápọ̀jù kí ó má baà wó irú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀. +Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ jẹ́ kí ó mọ̀ pé ẹ fẹ́ràn òun. +Ìdí tí mo fi kọ ìwé sí yín ni láti fi dán yín wò, kí n lè mọ̀ bí ẹ bá ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu ninu ohun gbogbo. +Ẹ Dárí Ji Ẹni Tí Ó Ṣe Àìdára. +Ṣé a óo ṣẹ̀ṣẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ láti máa ṣe àpèjúwe ara wa ni; àbí a nílò láti mú ìwé ẹ̀rí tọ̀ yín wá tí yóo sọ irú ẹni tí a jẹ́ fun yín, tabi kí á gbà lọ láti ọ̀dọ̀ yín? +Àní ohun tí ó lógo tẹ́lẹ̀ kò tún lógo mọ́ nítorí ohun mìíràn tí ògo tirẹ̀ ta á yọ. +Nítorí bí ohun tí yóo pada di asán bá lógo, mélòó-mélòó ni ti ohun tí yóo wà títí laelae? +Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ní irú ìrètí yìí, a ń fi ìgboyà pupọ sọ̀rọ̀. +A kò dàbí Mose tí ó fi aṣọ bojú rẹ̀, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà rí ògo ojú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni ògo tíí ṣá ni. +Ṣugbọn ọkàn wọn ti le, nítorí títí di ọjọ́ òní, aṣọ náà ni ó ń bo ọkàn wọn nígbà tí wọn bá ń ka ìwé majẹmu àtijọ́. Wọn kò mú aṣọ náà kúrò, nítorí nípasẹ̀ Kristi ni majẹmu àtijọ́ fi di asán. +Ṣugbọn títí di ọjọ́ òní, nígbàkúùgbà tí wọn bá ń ka Òfin Mose, aṣọ a máa bo ọkàn wọn. +Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ nípa Mose, “Nígbàkúùgbà tí ó bá yipada sí Oluwa, a mú aṣọ kúrò lójú.” +Ǹjẹ́ Oluwa tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni Ẹ̀mí Mímọ́. Níbikíbi tí Ẹ̀mí Oluwa bá wà, òmìnira wà níbẹ̀. +Kò sí aṣọ tí ó bò wá lójú. Ojú gbogbo wa ń fi ògo Oluwa hàn bí ìgbà tí eniyan ń wo ojú rẹ̀ ninu dígí. À ń pa wá dà sí ògo mìíràn tí ó tayọ ti àkọ́kọ́. Èyí jẹ́ iṣẹ́ Oluwa tí í ṣe Ẹ̀mí. +Ẹ̀yin alára ni ìwé wa, tí a ti kọ sí ọkàn wa. Gbogbo eniyan ni wọ́n mọ ìwé yìí, tí wọ́n sì ń kà á. +Ó hàn gbangba pé ẹ̀yin ni ìwé tí Kristi kọ, tí ó fi rán wa. Kì í ṣe irú èyí tí wọ́n fi yíǹkì kọ, Ẹ̀mí Ọlọrun alààyè ni wọ́n fi kọ ọ́. Kì í ṣe èyí tí wọ́n kọ sí orí òkúta; ọkàn eniyan ni wọ́n kọ ọ́ sí. +A lè sọ èyí nítorí a ní igbẹkẹle ninu Ọlọrun nípa Kristi. +Kì í ṣe pé a ní agbára tó ninu ara wa, tabi pé a ti lè ṣe nǹkankan fúnra wa. Ṣugbọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti ní gbogbo nǹkan ní ànító. +Ọlọrun ni ó mú kí á lè jẹ́ iranṣẹ ti majẹmu titun, tí kì í ṣe ti òfin tí a kọ bíkòṣe ti Ẹ̀mí. Nítorí ikú ni òfin tí a kọ sílẹ̀ ń mú wá, ṣugbọn majẹmu ti Ẹ̀mí ń sọ eniyan di alààyè. +Bí òfin tí a kọ sí ara òkúta tí ó jẹ́ iranṣẹ ikú bá wá pẹlu ògo, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè ṣíjú wo Mose, nítorí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn ní ojú rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, +báwo ni iranṣẹ ti Ẹ̀mí yóo ti lógo tó? +Bí iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa lẹ́bi bá lógo, báwo ni iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa láre yóo ti lógo tó? +Òjíṣẹ́ Majẹmu Titun. +Nítorí èyí, níwọ̀n ìgbà tí ó wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ láti fi iṣẹ́ yìí fún wa ṣe, ọkàn wa kò rẹ̀wẹ̀sì. +À ń ru ikú Jesu káàkiri lára wa nígbà gbogbo, kí ìyè Jesu lè hàn lára wa. +Nítorí pé nígbà gbogbo ni à ń fi ẹ̀mí wa wéwu nítorí Jesu, níwọ̀n ìgbà tí a wà láàyè, kí ìyè Jesu lè hàn ninu ẹran-ara wa tí yóo di òkú. +Ó wá jẹ́ pé ikú ní ń ṣiṣẹ́ ninu wa, nígbà tí ìyè ń ṣiṣẹ́ ninu yín. +Àkọsílẹ̀ kan sọ pé, “Mo gbàgbọ́, nítorí náà ni mo fi sọ̀rọ̀.” Nígbà tí ó ti jẹ́ pé a ní ẹ̀mí igbagbọ kan náà, àwa náà gbàgbọ́, nítorí náà ni a fi ń sọ̀rọ̀. +A mọ̀ pé ẹni tí ó jí Oluwa Jesu dìde yóo jí àwa náà dìde pẹlu Jesu, yóo wá mú àwa ati ẹ̀yin wá sí iwájú rẹ̀. +Nítorí tiyín ni gbogbo èyí, kí oore-ọ̀fẹ́ lè máa pọ̀ sí i fún ọpọlọpọ eniyan, kí ọpẹ́ yín lè máa pọ̀ sí i fún ògo Ọlọrun. +Nítorí náà ni a kò fi sọ ìrètí nù. Nítorí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara wa ti òde ń bàjẹ́, ṣugbọn ara wa ti inú ń di titun sí i lojoojumọ. +Ìjìyà wa mọ níwọ̀n, ati pé fún àkókò díẹ̀ ni. Àyọrísí rẹ̀ ni ògo tí ó pọ̀ pupọ, tí yóo wà títí, tí ó sì pọ̀ ju ìyà tí à ń jẹ lọ. +Kì í ṣe àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí ni a tẹjúmọ́, bíkòṣe àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí. Nítorí àwọn nǹkan tí yóo wà fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí. Àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí ni yóo wà títí laelae. +A ti kọ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ tíí máa ti eniyan lójú sílẹ̀. A kò hùwà ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni a kò yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ṣugbọn ọ̀nà tí a fi gba iyì ninu ẹ̀rí-ọkàn eniyan ati níwájú Ọlọrun ni pé à ń fi òtítọ́ hàn kedere. +Ṣugbọn tí ìyìn rere wa bá ṣókùnkùn, àwọn tí yóo ṣègbé ni ó ṣókùnkùn sí. +Àwọn oriṣa ayé yìí ni wọ́n fọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lójú, tí ọkàn wọn kò fi lè gbàgbọ́. Èyí ni kò jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ìyìn rere Kristi, tí ó lógo, kí ó tàn sí wọn lára; àní, Kristi tíí ṣe àwòrán Ọlọrun. +Nítorí kì í ṣe nípa ara wa ni à ń waasu. Ẹni tí à ń waasu rẹ̀ ni Jesu Kristi pé òun ni Oluwa. Iranṣẹ yín ni a jẹ́, nítorí ti Kristi. +Nítorí Ọlọrun tí ó ní kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn, òun ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, kí ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun lè tàn sí wa ní ojú Kristi. +Ṣugbọn bí ìkòkò amọ̀ ni àwa tí ìṣúra yìí wà ninu wa rí, kí ó lè hàn gbangba pé Ọlọrun ni ó ní agbára tí ó tóbi jùlọ, kì í ṣe àwa. +A ní oríṣìíríṣìí ìṣòro, ṣugbọn wọn kò wó wa mọ́lẹ̀; ọkàn wa ń dààmú, ṣugbọn a kò ṣe aláìní ìrètí. +Àwọn eniyan ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣugbọn Ọlọrun kò fi wá sílẹ̀. Wọ́n gbé wa ṣubú, ṣugbọn wọn kò lè pa wá. +Ìṣúra ti Ẹ̀mí ninu ìkòkò Amọ̀. +Nítorí a mọ̀ pé bí àgọ́ ara tí a fi ṣe ilé ní ayé yìí bá wó, a ní ilé kan lọ́dọ̀ Ọlọrun, tí a kò fi ọwọ́ kọ́, tí yóo wà lọ́run títí laelae. +Nítorí gbogbo wa níláti lọ siwaju Kristi bí a ti rí, láti lọ jẹ́ ẹjọ́. Níbẹ̀ ni olukuluku yóo ti gba ohun tí ó tọ́ sí i fún oríṣìíríṣìí ìwà tí ó ti hù nígbà tí ó wà ninu ara, ìbáà ṣe rere, ìbáà ṣe burúkú. +Nítorí náà nígbà tí àwa ti mọ ohun tí ìbẹ̀rù Oluwa jẹ́, a mọ̀ pé eniyan ni a lè gbìyànjú láti yí lọ́kàn pada. Ọlọrun mọ irú ẹni tí a jẹ́, mo sì rò pé ẹ̀rí-ọkàn yín jẹ́rìí sí mi pẹlu. +Kò tún nílò pé kí á máa pọ́n ara wa fun yín mọ́. Ṣugbọn èyí yóo jẹ́ anfaani fun yín láti máa fi wá ṣògo, kí ẹ lè máa rí ohun wí fún àwọn tí wọn ń ṣògo nípa nǹkan ti òde ara, tí kì í ṣe nípa nǹkan ti inú ọkàn. +Bí ó bá dàbí ẹni pé orí wa kò pé, nítorí ti Ọlọrun ni. Bí a bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n, a jẹ́ ẹ fun yín, +nítorí ìfẹ́ Kristi ni ó ń darí wa, nígbà tí a ti mọ̀ pé ẹnìkan ti kú fún gbogbo eniyan, a mọ̀ pé ikú gbogbo eniyan ni ó gbà kú. +Ìdí tí Kristi fi kú fún gbogbo eniyan ni pé kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe wà láàyè fún ara wọn, ṣugbọn kí wọ́n lè wà láàyè fún ẹni tí ó kú fún wa, tí Ọlọrun sì jí dìde. +Àyọrísí gbogbo èyí ni pé, láti ìgbà yìí lọ, àwa kò tún ní wo ẹnikẹ́ni ní ìwò ti ẹ̀dá mọ́. Nígbà kan ìwò ti ẹ̀dá ni à ń wo Kristi, ṣugbọn a kò tún wò ó bẹ́ẹ̀ mọ́. +Èyí ni pé nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà ninu Kristi, ó di ẹ̀dá titun. Ohun àtijọ́ ti kọjá lọ. Ìgbé-ayé irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì di titun. +Iṣẹ́ Ọlọrun ni èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Òun ni ó ti là wá níjà pẹlu ara rẹ̀ nípasẹ̀ Kristi. Òun kan náà ni ó tún fún wa ní iṣẹ́ ìlàjà ṣe. +Iṣẹ́ náà ni pé Ọlọrun wà ninu Kristi, ó ń làjà láàrin aráyé ati ara rẹ̀. Kò ka àwọn ìwà àìṣedéédé wọn sí wọn lọ́rùn. Ó sì ti wá fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́. +Nítorí ninu àgọ́ ara yìí à ń kérora, à ń tiraka láti gbé ilé wa ti ọ̀run wọ̀. +Nítorí náà, a jẹ́ aṣojú fún Kristi. Ó dàbí ẹni pé àwa ni Ọlọrun ń lò láti fi bẹ̀ yín. A fi orúkọ Kristi bẹ̀ yín, ẹ bá Ọlọrun rẹ́. +Kristi kò dẹ́ṣẹ̀. Sibẹ nítorí tiwa, Ọlọrun sọ ọ́ di ọ̀kan pẹlu ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀, kí á lè di olódodo níwájú Ọlọrun nípa rẹ̀. +A ní ìrètí pé bí a bá gbé e wọ̀, a kò ní bá ara wa níhòòhò. +Àwa tí a wà ninu àgọ́ ara yìí ń kérora nítorí pé ara ń ni wá, kò jẹ́ pé a fẹ́ bọ́ àgọ́ ara yìí sílẹ̀, ṣugbọn àgọ́ ara yìí ni a fẹ́ gbé ara titun wọ̀ lé, kí ara ìyè lè gbé ara ikú mì. +Ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ yìí lára wa ni Ọlọrun. Ó sì fún wa ní Ẹ̀mí Mímọ́, ó fi ṣe onídùúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí yóo tún fún wa. +Nítorí náà, a ní ìgboyà nígbà gbogbo. A mọ̀ pé níwọ̀n ìgbà tí a bá fi ara yìí ṣe ilé, a dàbí ẹni tí ó jáde kúrò lọ́dọ̀ Oluwa. +Nítorí igbagbọ ni a fi ń gbé ìgbé-ayé wa, kì í ṣe ohun tí à ń fi ojú rí. +Bí mo ti sọ, a ní ìgboyà. Inú wa ìbá sì dùn kí á kúrò ninu àgọ́ ti ara yìí, kí á bọ́ sinu ilé lọ́dọ̀ Oluwa. +Nítorí èyí, kì báà jẹ́ pé a wà ninu ilé ti ibí, tabi kí á bọ́ sinu ilé ti ọ̀hún, àníyàn wa ni pé kí á sá jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Oluwa. +Iṣẹ́ Ìlàjà. +Gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ má ṣe jẹ́ kí gbígbà tí ẹ gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jẹ́ lásán. +A ní ìrírí ìbànújẹ́ nígbà gbogbo, sibẹ à ń yọ̀. A jẹ́ aláìní, sibẹ a ti sọ ọpọlọpọ di ọlọ́rọ̀. A dàbí àwọn tí kò ní nǹkankan, sibẹ a ní ohun gbogbo. +A ti sọ òtítọ́ inú wa fun yín, ẹ̀yin ará Kọrinti. Ọkàn wa ṣípayá si yín. +Kò sí ohun kan ní ọkàn wa si yín. Bí ohun kan bá wà, a jẹ́ pé ní ọkàn tiyín ni. +Mò ń ba yín sọ̀rọ̀ bí ọmọ. Ohun tí ó yẹ yín ni pé kí ẹ ṣí ọkàn yín payá sí wa. +Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ àwọn alaigbagbọ. Nítorí ìrẹ́pọ̀ wo ni ó wà láàrin ìwà òdodo ati aiṣododo? Tabi, kí ni ó pa ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn pọ̀? +Báwo ni Kristi ti ṣe lè fi ohùn ṣọ̀kan pẹlu Èṣù? Kí ni ìbá pa onigbagbọ ati alaigbagbọ pọ̀? +Kí ni oriṣa ń wá ninu ilé Ọlọrun? Nítorí ilé Ọlọrun alààyè ni àwa jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ, pé, “N óo máa gbé ààrin wọn,n óo máa káàkiri ní ààrin wọn.N óo jẹ́ Ọlọrun wọn,wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi. +Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàrin wọn, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀, ni Oluwa wí.Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́,kí n lè gbà yín. +N óo jẹ́ baba fun yín, ẹ̀yin náà óo sì jẹ́ ọmọ fún mi,lọkunrin ati lobinrin yín.Èmi Oluwa Olodumare ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Nítorí Ọlọrun sọ pé, “Mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ nígbà tí o bá ojurere mi pàdé;mo ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ ìgbàlà.”Ìsinsìnyìí ni àkókò ojurere Ọlọrun. Òní ni ọjọ́ ìgbàlà. +A kò fi ohun ìkọsẹ̀ kankan siwaju ẹnikẹ́ni, kí àwọn eniyan má baà rí wí sí iṣẹ́ wa. +Ṣugbọn ninu gbogbo nǹkan, à ń fi ara wa sípò àyẹ́sí gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Ọlọrun. A ti fara da ọpọlọpọ nǹkan ní àkókò inúnibíni, ninu ìdààmú, ati ninu ìṣòro; +nígbà tí wọ́n nà wá ati nígbà tí a wà lẹ́wọ̀n, ní àkókò ìrúkèrúdò ati ní àkókò tí iṣẹ́ wọ̀ wá lọ́rùn, tí à ń pa ebi mọ́nú. +À ń ṣiṣẹ́ pẹlu ọkàn kan; pẹlu ọgbọ́n ati sùúrù, pẹlu inú rere ati ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, pẹlu ìfẹ́ tí kò lẹ́tàn. +À ń ṣe iṣẹ́ wa pẹlu òtítọ́ inú ati agbára Ọlọrun. A mú ohun ìjà òdodo lọ́wọ́ ọ̀tún ati lọ́wọ́ òsì. +Bí a ti ń gba ọlá, bẹ́ẹ̀ ni à ń gba ìtìjú. Bí a ti ń gba èébú, bẹ́ẹ̀ ni à ń gba ìyìn. Àwọn ẹlòmíràn kà wá sí ẹlẹ́tàn, bẹ́ẹ̀ sì ni olóòótọ́ ni wá. +Ìwà wa kò yé àwọn eniyan, sibẹ gbogbo eniyan ni ó mọ̀ wá. A dàbí ẹni tí ń kú lọ, sibẹ a tún wà láàyè. A ti ní ìrírí ìtọ́ni pẹlu ìjìyà, sibẹ ìjìyà yìí kò pa wá. +Ilé Ọlọrun Alààyè. +Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́, nígbà tí ẹ ti ní àwọn ìlérí yìí, ẹ wẹ gbogbo ìdọ̀tí kúrò ní ara ati ẹ̀mí yín. Ẹ ya ara yín sí mímọ́ patapata pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun. +Ìbànújẹ́ tí eniyan bà faradà gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́ a máa mú kí eniyan ronupiwada kí ó sì rí ìgbàlà, tí kò ní àbámọ̀ ninu. Ṣugbọn tí eniyan bá kàn ní ìbànújẹ́ lásán, ikú ni àyọrísí rẹ̀. +Ṣé ẹ wá rí i bí ìbànújẹ́ tí ẹ faradà gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́, ti yọrí sí fun yín? Ó mú kí ẹ fi ìtara mú ọ̀rọ̀ náà, kí ẹ sì jà fún ara yín. Ó mú kí inú bi yín sí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó mú ìbẹ̀rù wá sọ́kàn yín. Ó mú kí ẹ ṣe aájò mi. Ó mú kí ẹ ní ìtara. Ó mú kí ẹ rí i pé ẹ ṣe ẹ̀tọ́ ninu ọ̀ràn náà. Ní gbogbo ọ̀nà ẹ ti fihàn pé ọwọ́ yín mọ́ ninu ọ̀ràn náà. +Nígbà tí mo kọ ìwé tí mo kọ́ kọ, kì í ṣe nítorí ti ẹni tí ó ṣe àìdára, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ti ẹni tí wọ́n ṣe àìdára sí. Ṣugbọn mo kọ ọ́ kí ìtara yín lè túbọ̀ hàn níwájú Ọlọrun. +Ìdí rẹ̀ nìyí tí a fi ní ìtùnú.Lẹ́yìn pé a ní ìtùnú, a tún ní ayọ̀ pupọ nígbà tí a rí bí ayọ̀ Titu ti pọ̀ tó, nítorí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ láàrin gbogbo yín. +Nítorí bí mo bá ti sọ ohunkohun nípa yín, tí mo sì ti fi ọwọ́ yín sọ̀yà, ẹ kò dójú tì mí. Ṣugbọn bí ó ti jẹ́ pé òtítọ́ ni gbogbo nǹkan tí a ti sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ náà ni ọwọ́ yín tí a fi sọ̀yà fún Titu jẹ́ òtítọ́. +Inú Titu dùn si yín lọpọlọpọ nígbà tí ó ranti bí gbogbo yín ti múra láti ṣe ohun tí ó sọ fun yín ati bí ẹ ti gbà á pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì. +Mo láyọ̀ pé mo lè gbẹ́kẹ̀lé yín ninu ohun gbogbo. +Ẹ fi wá sọ́kàn. A kò ṣẹ ẹnikẹ́ni. A kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́. A kò sì rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. +Kì í ṣe pé mò ń fi èyí ba yín wí. Nítorí, bí mo ti sọ ṣáájú, ẹ ṣe ọ̀wọ́n fún wa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí ó bá kan ti ikú, kí á jọ kú ni, bí ó bá sì jẹ́ ti ìyè, kí á jọ wà láàyè ni. +Ọkàn mi balẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yín. Mò ń fi ọwọ́ yín sọ̀yà. Mò ti ní ìtùnú kíkún. Ninu gbogbo ìpọ́njú wa, mo ní ayọ̀ lọpọlọpọ. +Nígbà tí a dé Masedonia, ọkàn wa kò balẹ̀ rárá. Wahala ni lọ́tùn-ún lósì, ìjà lóde, ẹ̀rù ninu. +Ṣugbọn Ọlọrun tí ń tu àwọn tí ọkàn wọn bá rẹ̀wẹ̀sì ninu, ti tù wá ninu nígbà tí Titu dé. +Kì í sìí ṣe ti dídé tí ó dé nìkan ni, ṣugbọn ó ròyìn fún wa, gbogbo bí ẹ ti dá a lọ́kàn le ati gbogbo akitiyan yín lórí wa, bí ọkàn yín ti bàjẹ́ tó fún ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ati bí ẹ ti ní ìtara tó fún mi. Èyí mú kí inú mi dùn pupọ. +Bí ó bá jẹ́ pé ìwé tí mo kọ bà yín ninu jẹ́, n kò kábàámọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti kọ́ kábàámọ̀ pé ìwé náà bà yín lọ́kàn jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, +ṣugbọn nisinsinyii mo láyọ̀. Kì í ṣe nítorí pé ó bà yín lọ́kàn jẹ́, ṣugbọn nítorí pé bíbà tí ó bà yín lọ́kàn jẹ́ ni ó jẹ́ kí ẹ ronupiwada. Nítorí ẹ farada ìbànújẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́, kí ẹ má baà pàdánù nítorí ohun tí a ṣe. +Inú Paulu Dùn Nígbà Tí Ìjọ Ronupiwada. +Ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ mọ ohun tí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ti ṣe láàrin àwọn ìjọ Masedonia. +Èrò mi lórí ọ̀rọ̀ yìí ni pé ohun tí ó dára jùlọ fun yín ni. Nígbà tí kì í tíí ṣe pé ẹ ti ń ṣe é nìkan ni, ṣugbọn tìfẹ́tìfẹ́ ni ẹ ti fi ń ṣe é láti ọdún tí ó kọjá, +ó tó àkókò wàyí, ẹ ṣe é parí. Irú ìtara tí ẹ fẹ́ fi ṣe é ni kí ẹ fi parí rẹ̀. Kí ẹ ṣe é gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ní tó. +Bí ìfẹ́ láti mú ọrẹ wá bá wà, Ọlọrun gba ohun tí eniyan bá mú wá. Ọlọrun kò bèèrè ohun tí eniyan kò ní. +Kì í ṣe pé, kí àwọn ẹlòmíràn má ṣe nǹkankan, kí ó jẹ́ pé ẹ̀yin nìkan ni ọrùn yóo wọ̀. Ṣugbọn ọ̀ràn kí ẹ jọ pín in ṣe ní dọ́gba-dọ́gba ni. Ní àkókò yìí, ọ̀pọ̀ tí ẹ ní yóo mú kí ẹ lè pèsè fún àìní àwọn tí ẹ̀ ń rànlọ́wọ́. Ní ọjọ́ iwájú, ọ̀pọ̀ tí àwọn náà bá ní yóo mú kí wọ́n lè pèsè fún àìní yín. Ọ̀rọ̀ ojuṣaaju kò ní sí níbẹ̀. +Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, “Ẹni tí ó kó ọ̀pọ̀ kò ní jù, ẹni tí ó kó díẹ̀ kò ṣe aláìní tó.” +Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fi irú ìtara kan náà tí mo ní sí ọkàn Titu. +Nítorí nígbà tí a sọ pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín, pẹlu ayọ̀ ni ó fi gbà láti wá. Òun fúnrarẹ̀ tilẹ̀ ní àníyàn láti wá sọ́dọ̀ yín tẹ́lẹ̀. +A rán arakunrin tí ó lókìkí ninu gbogbo àwọn ìjọ nítorí iṣẹ́ rẹ̀ nípa ìyìn rere pé kí ó bá a wá. +Kì í ṣe pé ó lókìkí nìkan ni, ṣugbọn òun ni ẹni tí gbogbo àwọn ìjọ yàn pé kí ó máa bá wa kiri nípa iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ tí à ń ṣe fún ògo Oluwa ati láti fi ìtara wa hàn. +Wọ́n ní ọpọlọpọ ìdánwò nípa ìpọ́njú. Sibẹ wọ́n ní ayọ̀ pupọ. Wọ́n ṣe aláìní pupọ, sibẹ wọ́n lawọ́ gan-an. +À ń ṣe èyí kí ẹnikẹ́ni má baà rí nǹkan wí sí wa nípa ọ̀nà tí à ń gbà ṣe ètò ti ẹ̀bùn yìí. +Nítorí ète wa dára lójú Oluwa, ó sì dára lójú àwọn eniyan pẹlu. +A tún rán arakunrin wa tí a ti dánwò ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà ní ti ìtara rẹ̀ pé kí ó bá wọn wá. Nisinsinyii ó túbọ̀ ní ìtara pupọ nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé yín pupọ. +Ní ti Titu, ẹlẹgbẹ́ mi ati alábàáṣiṣẹ́ mi ni ninu ohun tí ó kàn yín. Ní ti àwọn arakunrin wa, òjíṣẹ́ àwọn ìjọ ni wọ́n, Ògo Kristi sì ni wọ́n. +Nítorí náà ẹ fi ìfẹ́ yín hàn sí wọn. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òtítọ́ ni àwọn nǹkan tí a sọ fún wọn, tí a sì fi ọwọ́ rẹ̀ sọ̀yà nípa yín. Ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo àwọn ìjọ bẹ́ẹ̀. +Nítorí mo jẹ́rìí pé wọ́n sa ipá wọn, wọ́n tilẹ̀ ṣe tayọ agbára wọn, tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n sì fi ṣe é. +Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìwúrí ni wọ́n fi bẹ̀ wá pé kí á jẹ́ kí àwọn náà lọ́wọ́ ninu iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ yìí fún àwọn onigbagbọ. +Wọ́n tilẹ̀ ṣe ju bí a ti lérò lọ, nítorí pé ara wọn pàápàá ni wọ́n kọ́ gbé bùn wá, tí wọ́n sì yọ̀ǹda fún Ọlọrun nípa ìfẹ́ rẹ̀. +Ìdí nìyí tí a fi gba Titu níyànjú pé, nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ yìí láàrin yín, kí ó kúkú ṣe é parí. +Gbogbo nǹkan wọnyi ni ẹ ní, tí ẹ sì ní lọpọlọpọ: igbagbọ, ọ̀rọ̀ sísọ, ìmọ̀, ati ìtara ní ọ̀nà gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tí ẹ ní sí wa. A fẹ́ kí ìtara yín túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìfẹ́ pẹlu. +N kò pa èyí láṣẹ. Mo fi àpẹẹrẹ ìtara àwọn ẹlòmíràn siwaju yín láti fi dán yín wò ni, bóyá ẹ ní ìfẹ́ tòótọ́ tabi ẹ kò ní. +Nítorí ẹ mọ oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi, pé nítorí tiwa, òun tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ di aláìní, kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípa àìní tirẹ̀. +Àwọn Onigbagbọ Ará Masedonia Lawọ́. +Nípa ti ìrànlọ́wọ́ fún àwọn onigbagbọ, kò nílò pé kí n tún kọ ìwé si yín mọ́. +Ṣugbọn ẹni tí ó ń pèsè irúgbìn fún afunrugbin, tí ó tún ń pèsè oúnjẹ fún jíjẹ, yóo pèsè èso lọpọlọpọ fun yín, yóo sì mú kí àwọn èso iṣẹ́ àánú yín pọ̀ sí i. +Ẹ óo jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ óo fi lè máa lawọ́ nígbà gbogbo. Ọpọlọpọ eniyan yóo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà tí a bá fún wọn ní ẹ̀bùn tí ẹ gbé kalẹ̀ nítorí ìlawọ́ yín. +Nítorí kì í ṣe àìní àwọn onigbagbọ nìkan ni iṣẹ́ ìsìn yìí yóo pèsè fún, ṣugbọn yóo mú kí ọpọlọpọ eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun. +Nítorí iṣẹ́ yìí jẹ́ ẹ̀rí tí àwọn eniyan yóo fi máa yin Ọlọrun fún rírẹ̀ tí ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ìgbọràn gẹ́gẹ́ bí ìjẹ́wọ́ igbagbọ yín ninu ìyìn rere ti Kristi, ati nítorí ìlawọ́ yín ninu iṣẹ́ yìí fún wọn ati fún gbogbo onigbagbọ. +Wọn yóo wá máa gbadura fun yín, ọkàn wọn yóo fà sọ́dọ̀ yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun lórí yín. +Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun nítorí ẹ̀bùn rẹ̀ tí kò ní òǹkà. +Nítorí mo mọ àníyàn yín, mo sì ti ń fi ọwọ́ sọ̀yà nípa yín fún àwọn ará Masedonia, pé Akaya ti parí ètò tiwọn láti ọdún tí ó kọjá. Ìtara yín sì ti mú kí ọpọlọpọ túbọ̀ múra sí i. +Mo rán àwọn arakunrin sí yín, kí ọwọ́ tí a fi ń sọ̀yà nípa yín lórí ọ̀rọ̀ yìí má baà jẹ́ lásán. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ, kí ẹ ti múra sílẹ̀. +Nítorí bí àwọn ará Masedonia bá bá mi wá sọ́dọ̀ yín, tí wọ́n wá rí i pé ẹ kò tíì múra sílẹ̀, ìtìjú ni yóo jẹ́ fún wa, kí á má wá sọ tiyín, nígbà tí a ti fi ọkàn tan yín lórí ọ̀rọ̀ yìí. +Nítorí náà, mo rí i pé ó di dandan pé kí n bẹ àwọn arakunrin láti ṣiwaju mi wá sọ́dọ̀ yín, kí wọ́n ṣe ètò sílẹ̀ nípa ẹ̀bùn tí ẹ ti ṣe ìlérí, kí ó jẹ́ pé yóo ti wà nílẹ̀ kí n tó dé. Èyí yóo mú kí ó jẹ́ ọrẹ àtinúwá, kò ní jẹ́ ti ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà. +Ẹ ranti pé ẹni tí ó bá fúnrúgbìn díẹ̀, díẹ̀ ni yóo kórè. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn pupọ, pupọ ni yóo kórè. +Kí olukuluku ṣe bí ó bá ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹlu ìkanra, tabi àfipáṣe, nítorí onínúdídùn ọlọ́rẹ ni Ọlọrun fẹ́. +Ọlọrun lè fun yín ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn, tí ẹ óo fi ní ànító ninu ohun gbogbo nígbà gbogbo. Ẹ óo sì tún ní tí yóo ṣẹ́kù fún ohun rere gbogbo. +Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹnìkan lawọ́, ó ń ta àwọn talaka lọ́rẹ, iṣẹ́ àánú rẹ̀ wà títí.” +Ọrẹ fún ��wọn Onigbagbọ. +Èmi Alàgbà ni mo kọ ìwé yìí sí àyànfẹ́ arabinrin ati àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ràn nítòótọ́. Kì í ṣe èmi nìkan ni mo fẹ́ràn rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òtítọ́ ni; +Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ yín tí kò mú ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má gbà á sílé. Ẹ má tilẹ̀ kí i, “Kú ààbọ̀.” +Ẹni tí ó bá kí i di alábàápín ninu àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀. +Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ba yín sọ pọ̀, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé. Mo ní ìrètí ati wá sọ́dọ̀ yín, kí á baà lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju, kí ayọ̀ wa lè di kíkún. +Àwọn ọmọ àyànfẹ́ arabinrin rẹ kí ọ. +nítorí òtítọ́ tí ó ń gbé inú wa, tí ó sì wà pẹlu wa yóo wà títí lae. +Oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi Ọmọ Baba yóo wà pẹlu wa ninu òtítọ́ ati ìfẹ́. +Mo láyọ̀ pupọ nítorí mo ti rí àwọn tí wọn ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́ ninu àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí a ti gba òfin lọ́dọ̀ Baba. +Nisinsinyii mo bẹ̀ ọ́, arabinrin, kì í ṣe pé mò ń kọ òfin titun sí ọ, yàtọ̀ sí èyí tí a ti níláti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ọmọnikeji wa. +Èyí ni ìfẹ́, pé kí á máa gbé ìgbé-ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin Ọlọrun. Bí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, òfin yìí ni pé kí ẹ máa rìn ninu ìfẹ́. +Ọpọlọpọ àwọn ẹlẹ́tàn ti dé inú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá ninu ara eniyan. Àwọn yìí ni ẹlẹ́tàn ati alátakò Kristi. +Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa iṣẹ́ tí ẹ ti ṣe run, kí ẹ lè gba èrè kíkún. +Ẹnikẹ́ni tí kò bá máa gbé inú ẹ̀kọ́ Kristi, ṣugbọn tí ó bá tayọ rẹ̀, kò mọ Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ẹ̀kọ́ Kristi mọ Baba ati Ọmọ. +Ìkíni. +Lẹ́yìn ikú Ahabu ọba, àwọn ará Moabu ṣọ̀tẹ̀ sí Israẹli, wọ́n fẹ́ fi tipátipá gba òmìnira. +Elija sì dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. +Ọba bá tún rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ-ogun rẹ̀ láti lọ mú Elija. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Elija òun náà tún sọ fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá kíákíá.” +Elija tún dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀ kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. +Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọba rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀. Ṣugbọn ó gòkè lọ sọ́dọ̀ Elija, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun jọ̀wọ́ mo bẹ̀ ọ́, ṣàánú fún mi ati fún àwọn iranṣẹ rẹ wọnyi, kí o sì dá ẹ̀mí wa sí. +Iná tí ó wá láti ọ̀run ni ó pa àwọn ọ̀gágun meji ti iṣaaju ati àwọn ọmọ ogun wọn, nítorí náà mo bẹ̀ ọ́, dá ẹ̀mí mi sí.” +Nígbà náà ni angẹli OLUWA sọ fún Elija pé kí ó bá wọn lọ, kí ó má sì bẹ̀rù. Elija bá bá a lọ sọ́dọ̀ ọba. +Elija sọ fún ọba pé, báyìí ni OLUWA wí, “Nítorí pé o rán oníṣẹ́ láti lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Baalisebubu, oriṣa Ekironi, bí ẹni pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli láti wádìí lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí náà, o kò ní sàn ninu àìsàn yìí, kíkú ni o óo kú.” +Ahasaya sì kú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA tí Elija sọ. Ṣugbọn nítorí pé kò ní ọmọkunrin kankan Joramu, arakunrin rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀, ní ọdún keji tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jọba ní Juda. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. +Ahasaya ọba ṣubú láti orí òkè ilé rẹ̀ ní Samaria, ó sì farapa pupọ. Nítorí náà ni ó ṣe rán oníṣẹ́ lọ bèèrè lọ́wọ́ Baalisebubu, oriṣa Ekironi, bóyá òun yóo sàn ninu àìsàn náà tabi òun kò ní sàn. +Ṣugbọn angẹli OLUWA kan pàṣẹ fún wolii Elija, ará Tiṣibe pé, “Lọ pàdé àwọn oníṣẹ́ ọba Samaria, kí o sì bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli ni ẹ fi ń lọ wádìí nǹkan lọ́dọ̀ Baalisebubu, oriṣa Ekironi?’ +Ẹ lọ sọ fún ọba pé, báyìí ni OLUWA wí, ‘O kò ní sàn ninu àìsàn náà, kíkú ni o óo kú.’ ”Elija sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. +Àwọn oníṣẹ́ náà pada sọ́dọ̀ ọba, ọba bá bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi pada?” +Wọ́n dáhùn pé, “Ọkunrin kan pàdé wa lọ́nà, ó sì sọ fún wa pé, ‘Ẹ pada sọ́dọ̀ ��ba tí ó ran yín, kí ẹ sì sọ fún un pé, “OLUWA ní, ṣé nítorí pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli ni o fi rán oníṣẹ́ lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Baalisebubu, oriṣa Ekironi? Nítorí náà o kò ní sàn ninu àìsàn yìí, o óo kú ni.” ’ ” +Ọba bá bèèrè pé, “Irú ọkunrin wo ni ó wá pàdé yín lójú ọ̀nà, tí ó sọ bẹ́ẹ̀ fun yín?” +Wọ́n dáhùn pé, “Ọkunrin náà wọ aṣọ tí wọ́n fi awọ ẹranko ṣe, ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́.” Ọba dáhùn pé, “Elija ará Tiṣibe ni.” +Ọba bá rán ọ̀gágun kan ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀ kí wọ́n lọ mú Elija. Ọ̀gágun náà rí Elija níbi tí ó jókòó sí ní téńté òkè, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá.” +Elija ati Ọba Ahasaya. +Ahabu ní aadọrin ọmọkunrin tí wọn ń gbé Samaria. Jehu kọ ìwé ranṣẹ sí àwọn olórí ìlú ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu, ó ní: +Èyí fihàn dájú pé gbogbo ohun tí OLUWA sọ nípa ìdílé Ahabu yóo ṣẹ. OLUWA ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí láti ẹnu Elija, wolii rẹ̀.” +Jehu pa gbogbo àwọn ìbátan Ahabu tí wọn ń gbé Jesireeli ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati àwọn alufaa; kò dá ọ̀kan ninu wọn sí. +Jehu kúrò ní Jesireeli, ó ń lọ sí Samaria. Nígbà tí ó dé ibìkan tí wọ́n ń pè ní Bẹtekedi, níbi tí àwọn olùṣọ́ aguntan ti máa ń rẹ́ irun aguntan, +ó pàdé àwọn ìbátan Ahasaya, ọba Juda, ó bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni yín?”Wọ́n dáhùn pé, “Ìbátan Ahasaya ni wá. Jesireeli ni à ń lọ láti lọ kí àwọn ọmọ ọba ati àwọn ìdílé ọba.” +Jehu pàṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mú wọn láàyè. Wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ibi kòtò tí ó wà ní Bẹtekedi. Gbogbo wọn jẹ́ mejilelogoji, kò sì dá ọ̀kankan ninu wọn sí. +Jehu tún ń lọ, ó pàdé Jehonadabu, ọmọ Rekabu, tí ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀. Lẹ́yìn tí Jehu kí i tán, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ọkàn rẹ mọ́ sí mi bí ọkàn mi ti mọ́ sí ọ?”Jehonadabu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”Jehu dáhùn, ó ní, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ rẹ.” Ó bá na ọwọ́ sí Jehu, Jehu sì fà á sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. +Ó ní, “Tẹ̀lé mi, kí o wá wo ìtara mi fún OLUWA.” Wọ́n sì jọ gun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ lọ sí Samaria. +Nígbà tí wọ́n dé Samaria, Jehu pa gbogbo àwọn ìbátan Ahabu, kò sì fi ọ̀kankan ninu wọn sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ láti ẹnu Elija. +Lẹ́yìn náà, Jehu pe gbogbo àwọn ará Samaria jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ahabu sin oriṣa Baali díẹ̀, ṣugbọn n óo sìn ín lọpọlọpọ. +Nítorí náà, ẹ pe gbogbo àwọn wolii Baali ati àwọn tí ń bọ ọ́ ati àwọn alufaa rẹ̀ wá fún mi. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe aláìwá nítorí mo fẹ́ ṣe ìrúbọ ńlá sí Baali. Ẹnikẹ́ni tí kò bá wá, pípa ni a óo pa á.” Ṣugbọn Jehu ń ṣe èyí láti rí ààyè pa gbogbo àwọn olùsìn Baali run ni. +“Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ọba, ẹ sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, ẹṣin, ati àwọn ohun ìjà ati àwọn ìlú olódi ní ìkáwọ́ yín. Nítorí náà, ní kété tí ẹ bá gba ìwé yìí, +Ó pàṣẹ pé, “Ẹ ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ìsìn Baali,” wọ́n sì kéde rẹ̀. +Jehu ranṣẹ sí àwọn ẹlẹ́sìn Baali ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli; kò sí ẹnìkan ninu wọn tí kò wá. Gbogbo wọn lọ sinu ilé ìsìn Baali, wọ́n sì kún inú rẹ̀ títí dé ẹnu ọ̀nà kan sí ekeji. +Jehu sì pàṣẹ fún ẹni tí ń tọ́jú ibi tí wọn ń kó aṣọ ìsìn pamọ́ sí pé kí ó kó wọn jáde fún àwọn tí ń bọ Baali. +Lẹ́yìn èyí, Jehu ati Jehonadabu lọ sinu ilé ìsìn náà, ó ní, “Ẹ rí i dájú pé àwọn olùsìn Baali nìkan ni wọ́n wà níhìn-ín, ati pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ń sin OLUWA níbí.” +Òun pẹlu Jehonadabu bá wọlé láti rú ẹbọ sísun sí Baali. Ṣugbọn Jehu ti fi ọgọrin ọkunrin yí ilé ìsìn náà po, ó sì ti pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn tí wọ́n wá jọ́sìn níbẹ̀. Ó ní ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ kí ẹnìkan lọ, pípa ni a óo pa á. +Ní kété tí Jehu parí rírú ẹbọ sísun rẹ̀, ó pàṣẹ fún àwọn olùṣọ́ ati àwọn olórí ogun pé kí wọ́n wọlé, kí wọ́n sì pa gbogbo wọn; ẹnikẹ́ni kò si gbọdọ̀ jáde. Wọ́n bá wọlé, wọ́n fi idà pa gbogbo wọn, wọ́n sì wọ́ òkú wọn síta. Lẹ́yìn náà, wọ́n wọ inú ibi mímọ́ Baali lọ, +wọ́n kó gbogbo àwọn ère tí wọ́n wà níbẹ̀ jáde, wọ́n sì sun wọ́n níná. +Wọ́n wó àwọn ère ati ilé ìsìn Baali lulẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilé ìgbẹ́ títí di òní y��í. +Bẹ́ẹ̀ ni Jehu ṣe pa ìsìn Baali run ní Israẹli. +Ṣugbọn Jehu tẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú kí Israẹli bọ ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù, tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ó wà ní Bẹtẹli ati Dani. +ẹ fi èyí tí ó bá jẹ́ akọni jùlọ lára àwọn ọmọ ọba sí orí oyè, ẹ sì múra láti jà fún ilẹ̀ oluwa yín.” +OLUWA sọ fún Jehu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó dára lójú mi, o ti ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe sí ilé Ahabu, tí o ṣe ohun tí ó wà lọ́kàn mi, àwọn ọmọ rẹ, títí dé ìran kẹrin, yóo máa jọba ní Israẹli.” +Ṣugbọn Jehu kò kíyèsára kí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀lé Òfin OLUWA Ọlọrun Israẹli; ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu tí ó mú kí Israẹli hù ni ó tẹ̀lé. +Ní àkókò náà ni OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí dín ilẹ̀ Israẹli kù. Hasaeli ọba Siria gba gbogbo àwọn agbègbè Israẹli, +láti ìhà ìlà oòrùn Jọdani, gbogbo ilẹ̀ Gileadi ati ti ẹ̀yà Gadi, ẹ̀yà Reubẹni ati ẹya Manase. Láti Aroeri tí ó wà ní àfonífojì Arinoni tíí ṣe ilẹ̀ Gileadi ati ilẹ̀ Baṣani. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehu ṣe, ati bí ó ti lágbára tó, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. +Jehu kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sí Samaria, Jehoahasi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Gbogbo àkókò tí Jehu fi jọba lórí Israẹli ní Samaria jẹ́ ọdún mejidinlọgbọn. +Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n ní, “Ǹjẹ́ àwa lè bá Jehu, ẹni tí ó ṣẹgun ọba meji jà?” +Nítorí náà, ẹni tí ó ń ṣe ìtọ́jú ààfin ati olórí ìlú pẹlu àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu ranṣẹ sí Jehu, wọ́n ní: “Iranṣẹ rẹ ni wá, a sì ti ṣetán láti ṣe ohunkohun tí o bá pa láṣẹ. A kò ní fi ẹnikẹ́ni sórí oyè, ṣe ohunkohun tí o bá rò pé ó dára.” +Jehu tún kọ ìwé mìíràn sí wọn, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ wà lẹ́yìn mi, ẹ sì ṣetán láti tẹ̀lé àṣẹ mi, ẹ kó orí àwọn ọmọ ọba Ahabu wá fún mi ní Jesireeli ní àkókò yìí ní ọ̀la.”Àwọn aadọrin ọmọ Ahabu náà wà ní abẹ́ ìtọ́jú àwọn àgbààgbà ìlú Samaria. +Nígbà tí wọ́n rí ìwé Jehu gbà, àwọn olórí Samaria pa gbogbo àwọn ọmọ Ahabu, wọ́n sì kó orí wọn sinu apẹ̀rẹ̀ lọ fún Jehu ní Jesireeli. +Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ fún Jehu pé wọ́n ti kó orí àwọn ọmọ Ahabu dé, ó pàṣẹ pé kí wọ́n kó wọn jọ sí ọ̀nà meji ní ẹnubodè ìlú, títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. +Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Jehu lọ sí ẹnubodè ìlú, ó sì sọ fún àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ pé, “Ẹ kò ní ẹ̀bi, èmi ni mo ṣọ̀tẹ̀ sí Joramu ọba, oluwa mi, tí mo sì pa á. Ṣugbọn ta ni ó pa àwọn wọnyi? +A Pa Àwọn Ọmọ Ọba Ahabu. +Ní kété tí Atalaya, ìyá ọba Ahasaya gbọ́ nípa ikú ọmọ rẹ̀, ó pa gbogbo ìdílé ọba run. +Jehoiada bá fún àwọn olórí ogun náà ní àwọn ọ̀kọ̀ ati apata Dafidi, tí wọ́n kó pamọ́ sinu ilé OLUWA. +Àwọn ọmọ ogun sì dúró pẹlu ohun ìjà lọ́wọ́ wọn láti ìhà gúsù ilé náà títí dé ìhà àríwá rẹ̀, wọ́n yí pẹpẹ ati ilé náà ká. +Lẹ́yìn náà ni ó mú Joaṣi, ọmọ ọba jáde síta, ó fi adé ọba dé e lórí, ó sì fún un ní ìwé òfin. Lẹ́yìn náà ni ó da òróró sí i lórí láti fi jọba. Àwọn eniyan pàtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe pé, “Kabiyesi, kí ẹ̀mí ọba ó gùn!” +Nígbà tí Atalaya gbọ́ ariwo àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ati ti àwọn eniyan, ó jáde lọ sí ilé OLUWA níbi tí àwọn eniyan péjọ sí. +Nígbà tí ó wo ọ̀kánkán, ó wò, ó rí ọba náà tí ó dúró ní ẹ̀bá òpó, ní ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí àṣà, ó sì rí i tí àwọn olórí ogun ati àwọn afunfèrè yí i ká, tí àwọn eniyan sì ń fi ayọ̀ pariwo, tí wọ́n sì ń fọn fèrè. Atalaya fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó sì kígbe pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí! Ọ̀tẹ̀ nìyí!” +Jehoiada kò fẹ́ kí wọ́n pa Atalaya ninu ilé OLUWA, nítorí náà ó pàṣẹ fún àwọn olórí ogun, ó ní, “Ẹ mú un jáde, kí ó wà ní ààrin yín bí ẹ ti ń mú un lọ; ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gbà á là, pípa ni kí ẹ pa á.” +Wọ́n bá mú un gba ẹnu ọ̀nà tí àwọn ẹṣin máa ń gbà wọ ààfin, wọ́n sì pa á. +Jehoiada alufaa mú kí Joaṣi ọba ati àwọn eniyan dá majẹmu pẹlu OLUWA pé àwọn yóo jẹ́ tirẹ̀; ó sì tún mú kí àwọn eniyan náà bá ọba dá majẹmu. +Lẹ́yìn náà, àwọn eniyan lọ sí ilé oriṣa Baali, wọ́n wó o, wọ́n sì wó àwọn pẹpẹ rẹ̀ ati àwọn ère rẹ̀ lulẹ̀. Wọ́n pa Matani, alufaa Baali, níwájú àwọn pẹpẹ náà.Jehoiada sì fi àwọn olùṣọ́ tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ sí ìtọ́jú ilé OLUWA. +Òun ati àwọn olórí ogun ati àwọn tí wọ́n ń ṣọ́ ọba ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin sin ọba láti ilé OLUWA lọ sí ààfin. Ọba gba ẹnu ọ̀nà àwọn olùṣọ́ wọlé, ó sì jókòó lórí ìtẹ́. +Joaṣi ọmọ Ahasaya nìkan ni kò pa nítorí pé Jehoṣeba ọmọbinrin Joramu ọba, arabinrin Ahasaya, gbé e sá lọ; ó sì fi òun ati alágbàtọ́ rẹ̀ pamọ́ sí yàrá kan ninu ilé OLUWA, kí Atalaya má baà pa á. Ó gbé e pamọ́ fún Atalaya, Atalaya kò sì rí i pa. +Gbogbo àwọn eniyan kún fún ayọ̀, gbogbo ìlú sì ní alaafia lẹ́yìn tí wọ́n ti fi idà pa Atalaya ní ààfin. +Ọmọ ọdún meje ni Joaṣi nígbà tí ó jọba. +Joaṣi wà ní ìpamọ́ ninu ilé OLUWA fún ọdún mẹfa, Atalaya sì ń jọba lórí ilẹ̀ Juda. +Ṣugbọn ní ọdún keje, Jehoiada ranṣẹ pe àwọn olórí ogun tí wọn ń ṣọ́ ọba wá sí ilé OLUWA pẹlu àwọn olórí ogun tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Ó bá wọn dá majẹmu, ó sì mú kí wọ́n búra láti fọwọsowọpọ pẹlu òun ninu ohun tí ó fẹ́ ṣe. Lẹ́yìn náà, ó fi ọmọ Ahasaya ọba hàn wọ́n. +Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ìdámẹ́ta yín tí ó bá wá sí ibi iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi yóo máa ṣọ́ ààfin. +(Ìdámẹ́ta yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà Suri; ìdámẹ́ta yòókù yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà tí ó wà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin), wọn yóo dáàbò bo ààfin. +Àwọn ìpín mejeeji tí wọ́n bá ṣíwọ́ iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi, yóo wá dúró ní ilé OLUWA láti dáàbò bo ọba. +Wọn yóo dáàbò bo ọba pẹlu idà ní ọwọ́ wọn, wọn yóo sì máa bá a lọ sí ibikíbi tí ó bá ń lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.” +Àwọn olórí ogun náà gbọ́ àṣẹ tí Jehoiada, alufaa, pa fún wọn, wọ́n sì kó àwọn ọmọ ogun wọn, tí wọ́n ṣíwọ́ iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ati àwọn tí wọn yóo wọ iṣẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. +Atalaya Ayaba Juda. +Ní ọdún keje tí Jehu jọba ní Israẹli ni Joaṣi jọba ní ilẹ̀ Juda, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ogoji ọdún. Sibaya tí ó wá láti ìlú Beeriṣeba ni ìyá rẹ̀. +Nígbà tí owó bá pọ̀ ninu àpótí náà, akọ̀wé ọba ati olórí Alufaa yóo ka owó náà, wọn yóo sì dì í sinu àpò. +Lẹ́yìn tí wọ́n bá wọn owó náà, wọn yóo gbé àpò owó náà fún àwọn tí wọn ń ṣe àkóso ilé OLUWA. Àwọn ni wọn yóo san owó fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn tí wọn ń kọ́lé; +ati fún àwọn ọ̀mọ̀lé, ati àwọn agbẹ́kùúta. Ninu rẹ̀, wọn yóo ra igi ati òkúta tí wọn yóo lò fún àtúnṣe náà ati láti san owó gbogbo ohun tí wọ́n nílò fún àtúnṣe ilé OLUWA. +Wọn kò lò lára owó náà láti fi ra agbada fadaka, abọ́, fèrè, tabi àwọn ohun èlò wúrà tabi ti fadaka sí ilé OLUWA, +ṣugbọn wọn ń lò ó láti fi san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ ati láti ra àwọn ohun èlò fún àtúnṣe ilé OLUWA. +Wọn kò sì bèèrè àkọsílẹ̀ iye tí àwọn tí wọn ń ṣàkóso iṣẹ́ náà ná nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́. +Ṣugbọn wọn kò da owó ìtanràn ati owó ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ mọ́ owó fún àtúnṣe ilé OLUWA, nítorí pé àwọn alufaa ni wọ́n ni owó ìtanràn ati ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. +Ní àkókò náà, Hasaeli, ọba Siria gbógun ti ìlú Gati, ó sì ṣẹgun rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó dojú kọ Jerusalẹmu, +Joaṣi, ọba Juda, kó gbogbo àwọn ẹ̀bùn mímọ́ tí Jehoṣafati ati Jehoramu ati Ahasaya, àwọn baba ńlá rẹ̀ tí wọ́n ti jọba ṣáájú rẹ̀ yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati èyí tí òun pàápàá ti yà sọ́tọ̀ ati gbogbo wúrà tí ó wà ninu àwọn ilé ìṣúra ilé OLUWA ati èyí tí ó wà ní ààfin, ó fi wọ́n ranṣẹ sí Hasaeli, ọba Siria. Hasaeli bá kó ogun rẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Joaṣi ọba ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. +Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA nítorí pé Jehoiada alufaa ń tọ́ ọ sọ́nà. +Àwọn olórí ogun Joaṣi ọba dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní ilẹ̀ Milo ní ọ̀nà tí ó lọ sí Sila. +Josakari, ọmọ Ṣimeati ati Jehosabadi, ọmọ Ṣomeri, àwọn olórí ogun, ni wọ́n pa á. Wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Amasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ṣugbọn kò ba àwọn pẹpẹ ìrúbọ jẹ́, àwọn eniyan ń rú ẹbọ níbẹ̀, wọ́n sì ń jó turari. +Joaṣi pàṣẹ fún àwọn alufaa pé kí wọ́n máa kó àwọn owó ohun mímọ́ tí wọ́n mú wá sí ilé OLUWA pamọ́: ati gbogbo owó tí àwọn eniyan san fún ẹbọ ìgbà gbogbo ati èyí tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá. +Alufaa kọ̀ọ̀kan ni yóo máa tọ́jú owó tí wọ́n bá mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, yóo sì lo owó náà láti máa tún ilé OLUWA ṣe bí ó ti fẹ́. +Àwọn alufaa náà kò tún nǹkankan ṣe ninu ilé OLUWA títí tí ó fi di ọdún kẹtalelogun tí Joaṣi ti jọba. +Nítorí náà, ó pe Jehoiada ati àwọn alufaa yòókù, ó bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ kò fi tún ilé OLUWA ṣe? Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹ gbọdọ̀ máa kó owó tí ẹ bá gbà sílẹ̀ fún àtúnṣe ilé OLUWA.” +Àwọn alufaa náà gba ohun tí ọba sọ, wọ́n sì gbà pé àwọn kò ní máa gba owó lọ́wọ́ àwọn eniyan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní tún ilé OLUWA ṣe fúnra wọn. +Nígbà náà ni Jehoiada gbé àpótí kan, ó lu ihò sí orí rẹ̀, ó gbé e sí ẹ̀bá pẹpẹ ìrúbọ ní ọwọ́ ọ̀tún tí eniyan bá wọ ilé OLUWA. Gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA a sì máa kó owó tí àwọn eniyan bá mú wá sinu rẹ̀. +Joaṣi Ọba Juda. +Ní ọdún kẹtalelogun tí Joaṣi, ọmọ Ahasaya, jọba ní Juda ni Jehoahasi, ọmọ Jehu, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó jọba fún ọdún mẹtadinlogun. +Ní ọdún kẹtadinlogoji tí Joaṣi jọba ní Juda ni Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, jọba lórí Israẹli ní Samaria. Ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun. +Òun náà ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoaṣi ṣe ati ìwà akọni rẹ̀ ninu ogun tí ó bá Amasaya, ọba Juda, jà ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. +Jehoaṣi kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba Israẹli ní Samaria. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Nígbà tí wolii Eliṣa wà ninu àìsàn tí ó le, tí ó sì ń kú lọ, Jehoaṣi, ọba Israẹli lọ bẹ̀ ẹ́ wò, nígbà tí ó rí Eliṣa, ó sọkún, ó sì ń kígbe pé, “Baba mi, baba mi! Ìwọ tí o jẹ́ alátìlẹyìn pataki fún Israẹli!” +Eliṣa bá sọ fún un pé kí ó mú ọrun ati ọfà, ó sì mú wọn. +Eliṣa sọ fún un pé kí ó múra láti ta ọfà náà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Eliṣa gbé ọwọ́ lé ọwọ́ ọba, +ó ní kí ọba ṣí fèrèsé, kí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ọba sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, Eliṣa pàṣẹ fún un pé kí ó ta ọfà náà. Bí ọba ti ta ọfà ni Eliṣa ń wí pé, “Ọfà ìṣẹ́gun OLUWA, ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria! Nítorí pé o óo bá àwọn Siria jagun ní Afeki títí tí o óo fi ṣẹgun wọn.” +Eliṣa tún ní kí ọba máa ta àwọn ọfà yòókù sílẹ̀. Nígbà tí ó ta á lẹẹmẹta, ó dáwọ́ dúró. +Èyí bí Eliṣa ninu, ó sì sọ fún ọba pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o ta ọfà náà nígbà marun-un tabi mẹfa ni, ò bá ṣẹgun Siria patapata, ṣugbọn báyìí, ìgbà mẹta ni o óo ṣẹgun wọn.” +Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ náà sílẹ̀. +Eliṣa kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀.Ní ọdọọdún ni àwọn ọmọ ogun Moabu máa ń gbógun ti ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli. +Ní ìgbà kan, bí wọ́n ti fẹ́ máa sìnkú ọkunrin kan, wọ́n rí i tí àwọn ọmọ ogun Moabu ń bọ̀, wọ́n bá ju òkú náà sinu ibojì Eliṣa. Bí ọkunrin náà ti fi ara kan egungun Eliṣa, ó sọjí, ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. +Hasaeli ọba Siria kò fi àwọn ọmọ Israẹli lọ́kàn balẹ̀ ní gbogbo àkókò ìjọba Jehoahasi. +Ṣugbọn OLUWA ṣàánú fún wọn, ó sì yipada sí wọn nítorí majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; kò sì gbàgbé àwọn eniyan rẹ̀. +Nígbà tí Hasaeli Ọba kú, Benhadadi ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Jehoaṣi ọba, ọmọ Jehoahasi, ṣẹgun Benhadadi ní ìgbà mẹta, ó sì gba àwọn ìlú tí wọ́n ti gbà ní ìgbà ayé Jehoahasi, baba rẹ̀ pada. +OLUWA bínú sí Israẹli, ó sì jẹ́ kí Hasaeli, ọba Siria, ati Benhadadi ọmọ rẹ̀ ṣẹgun Israẹli ní ọpọlọpọ ìgbà. +Nígbà tí Jehoahasi gbadura sí OLUWA, tí OLUWA sì rí ìyà tí Hasaeli fi ń jẹ àwọn eniyan Israẹli, ó gbọ́ adura rẹ̀. +(Nítorí náà, OLUWA rán olùgbàlà kan sí Israẹli láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Siria, ọkàn àwọn eniyan Israẹli sì balẹ̀ bíi ti ìgbà àtijọ́. +Sibẹsibẹ wọn kò yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu ti mú Israẹli dá. Wọ́n sì tún ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kan náà, ère oriṣa Aṣera sì wà ní Samaria.) +Jehoahasi kò ní àwọn ọmọ ogun mọ́ àfi aadọta ẹlẹ́ṣin, ati kẹ̀kẹ́ ogun mẹ́wàá ati ẹgbaarun (10,000) àwọn ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn. Ọba Siria ti pa gbogbo wọn run, ó lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi erùpẹ̀. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoahasi ṣe ati agbára rẹ̀ ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. +Ó kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀ sí Samaria. Jehoaṣi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Jehoahasi Ọba Israẹli. +Ní ọdún keji tí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi jọba ní Israẹli ni Amasaya ọmọ Joaṣi jọba ní Juda. +Nisinsinyii, ìwọ Amasaya, nítorí pé o ti ṣẹgun Edomu, ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga. Jẹ́ kí ògo rẹ yìí tẹ́ ọ lọ́rùn, kí ló dé tí o fi fẹ́ dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ sí ìparun ara rẹ ati ti Juda?” +Ṣugbọn Amasaya kọ̀ kò gbọ́, nítorí náà, Jehoaṣi ọba Israẹli kó ogun lọ pàdé Amasaya ọba Juda ní Beti Ṣemeṣi tí ó wà ní Juda. +Israẹli ṣẹgun Juda, gbogbo àwọn ọmọ ogun Juda sì pada sí ilé wọn. +Ọwọ́ Jehoaṣi tẹ Amasaya, lẹ́yìn náà, ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Igun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ irinwo igbọnwọ (400 mita). +Ó kó gbogbo fadaka ati wúrà tí ó rí ati gbogbo àwọn ohun èlò ilé OLUWA ati gbogbo ohun tí ó níye lórí ní ààfin, ó sì pada sí Samaria. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoaṣi ṣe, ati ìwà akọni rẹ̀ ninu ogun tí ó bá Amasaya jà, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. +Jehoaṣi kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba ní Samaria. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Amasaya ọba, ọmọ Joaṣi gbé ọdún mẹẹdogun lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọba Israẹli. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Amasaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. +Wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Amasaya Ọba ní Jerusalẹmu, ó sì sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n rán eniyan lọ bá a níbẹ̀, wọ́n sì pa á. +Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn ní Jerusalẹmu. Jehoadini, ará Jerusalẹmu, ni ìyá rẹ̀. +Wọ́n gbé òkú rẹ̀ sórí ẹṣin wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba, ní ìlú Dafidi. +Àwọn eniyan Juda sì fi Asaraya, ọmọ rẹ̀, jọba. Ẹni ọdún mẹrindinlogun ni, nígbà tí ó jọba. +Asaraya tún ìlú Elati kọ́, ó sì dá a pada fún Juda lẹ́yìn ikú baba rẹ̀. +Ní ọdún kẹẹdogun tí Amasaya ọmọ Joaṣi jọba ní Juda ni Jeroboamu, ọmọ Jehoaṣi, ọba Israẹli jọba ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkanlelogoji. +Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA; ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. +Ó gba gbogbo ilẹ̀ Israẹli pada láti ẹnubodè Hamati títí dé Òkun Araba, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ láti ẹnu wolii rẹ̀, Jona, ọmọ Amitai, ará Gati Heferi. +OLUWA rí i pé ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli pọ̀, kò sì sí ẹni tí ìpọ́njú náà kò kàn, ati ẹrú ati ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́. +Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò tíì sọ pé òun óo pa gbogbo Israẹli run, nítorí náà, ó ṣẹgun fún wọn láti ọwọ́ Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Jeroboamu ṣe, ìwà akọni rẹ̀ lójú ogun ati bí ó ti gba Damasku ati Hamati, tí wọ́n jẹ́ ti Juda tẹ́lẹ̀ rí, fún Israẹli, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. +Jeroboamu kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba, Sakaraya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ṣugbọn kò dàbí ti Dafidi baba ńlá rẹ̀; ohun gbogbo tí Joaṣi baba rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe. +Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ oriṣa run; àwọn eniyan ṣì ń rú ẹbọ níbẹ̀, wọ́n sì ń sun turari. +Nígbà tí ìjọba rẹ̀ fìdí múlẹ̀ tán, ó pa àwọn olórí ogun tí wọ́n pa baba rẹ̀. +Ṣugbọn kò pa àwọn ọmọ wọn nítorí pé òfin Mose pa á láṣẹ pé, “A kò gbọdọ̀ pa baba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọdọ̀ pa ọmọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba. Olukuluku ni yóo kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” +Amasaya pa ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ọmọ ogun Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀. Ó ṣẹgun Sela, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jokiteeli, orúkọ yìí ni ìlú náà ń jẹ́ títí di òní yìí. +Lẹ́yìn náà, Amasaya ranṣẹ sí Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu, ọba Israẹli, láti pè é níjà sí ogun. +Ṣugbọn Jehoaṣi ọba ranṣẹ pada pẹlu òwe yìí: Ó ní, “Ní ìgbà kan ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún kan tí ó wà ní Lẹbanoni ranṣẹ sí igi kedari ní Lẹbanoni pé, ‘Fi ọmọbinrin rẹ fún ọmọkunrin mi ní aya.’ Ṣugbọn ẹranko burúkú kan tí ó wà ní Lẹbanoni ń kọjá lọ, ó sì tẹ ẹ̀gún náà mọ́lẹ̀. +Amasaya Ọba Juda. +Ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Jeroboamu jọba ní Israẹli ni Asaraya ọmọ Amasaya, jọba ní Juda. +Ṣalumu ọmọ Jabeṣi dìtẹ̀ mọ́ ọn, ó pa á ní Ibileamu, ó sì jọba dípò rẹ̀. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Sakaraya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. +OLUWA ṣèlérí fún Jehu pé, “Àwọn ọmọ rẹ títí dé ìran kẹrin yóo jọba ní Israẹli.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. +Ní ọdún kọkandinlogoji tí Asaraya ti jọba ní Juda ni Ṣalumu, ọmọ Jabeṣi, jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó wà lórí oyè fún oṣù kan. +Menahemu ọmọ Gadi lọ sí Samaria láti Tirisa, ó pa Ṣalumu ọba, ó sì jọba dípò rẹ̀. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Ṣalumu ṣe, ati ìwà ọ̀tẹ̀ tí ó hù ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. +Ní àkókò náà Menahemu pa ìlú Tapua run, ati àwọn ìlú tí wọ́n yí i ká láti Tirisa, nítorí pé wọn kò ṣí ìlẹ̀kùn ìlú náà fún un, ó sì la inú gbogbo àwọn aboyún tí wọ́n wà níbẹ̀. +Ní ọdún kọkandinlogoji tí Asaraya jọba ní Juda, ni Menahemu, ọmọ Gadi, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹ́wàá. +Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, nítorí pé ó tẹ̀lé ọ̀nà Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. +Pulu, tí à ń pè ní Tigilati Pileseri, ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ Israẹli; kí ó baà lè ran Menahemu lọ́wọ́ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, Menahemu fún un ní ẹgbẹrun (1,000) talẹnti owó fadaka. +Ẹni ọdún mẹrindinlogun ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mejilelaadọta. Jekolaya ará Jerusalẹmu ni ìyá rẹ̀. +Ọwọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ Israẹli ni ọba ti gba owó náà, ó pàṣẹ pé kí olukuluku dá aadọta ṣekeli owó fadaka. Ọba Asiria bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Menahemu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. +Ó kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀, Pekahaya, ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Nígbà tí ó di aadọta ọdún tí Asaraya jọba ní Juda, ni Pekahaya, ọmọ Menahemu jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji. +Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA; ó sì tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. +Peka, ọmọ Remalaya, olórí ogun rẹ̀, pẹlu aadọta ọmọ ogun Gileadi dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní Samaria, ninu ilé tí a mọ odi tí ó lágbára yíká, tí ó wà ninu ààfin rẹ̀, Peka sì jọba dípò rẹ̀. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Pekahaya ṣe, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. +Ní ọdún kejilelaadọta tí Asaraya jọba ní Juda, ni Peka, ọmọ Remalaya, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ogún ọdún. +Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. +Ní àkókò tí Peka jọba Israẹli ni Tigilati Pileseri, ọba Asiria, gba ìlú Ijoni, Abeli Beti Maaka, Janoa, Kedeṣi, Hasori, ati ilẹ̀ Gileadi, Galili ati gbogbo ilẹ̀ Nafutali, ó sì kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rú lọ sí Asiria. +Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀lé ọ̀nà Amasaya, baba rẹ̀. +Ní ogún ọdún tí Jotamu, ọmọ Usaya jọba Juda, ni Hoṣea, ọmọ Ela, dìtẹ̀ mọ́ Peka ọba, ó pa á, ó sì jọba dípò rẹ̀. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Peka ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. +Ní ọdún keji tí Peka ọmọ Remalaya, jọba ní Israẹli, ni Jotamu, ọmọ Usaya, jọba ní Juda. +Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì jọba fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jeruṣa, ọmọ Sadoku. +Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀ sí ọ̀nà Usaya, baba rẹ̀. +Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run, àwọn eniyan ṣì ń rú ẹbọ, wọ́n sì ń sun turari níbẹ̀. Òun ni ó kọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìhà àríwá ilé OLUWA. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Jotamu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. +Ní àkókò tí ó jọba ni OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí rán Resini, ọba Siria, ati Peka, ọmọ Remalaya, tí í ṣe ọba Israẹli, láti gbógun ti Juda. +Jotamu kú, wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi; Ahasi ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ oriṣa run, àwọn eniyan ṣì ń rúbọ; wọ́n sì ń sun turari níbẹ̀. +OLUWA sọ Asaraya ọba di adẹ́tẹ̀, ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, ó ń dá gbé. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì ń ṣàkóso ìjọba nípò rẹ̀. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Asaraya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. +Ó kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi, Jotamu, ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ní ọdún kejidinlogoji tí Asaraya jọba ní Juda ni Sakaraya ọmọ Jeroboamu jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún oṣù mẹfa. +Ó ṣe ohun burúkú níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe. Ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu; ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. +Asaraya Ọba Juda. +Ní ọdún kẹtadinlogun tí Peka, ọmọ Remalaya, jọba ní Israẹli, ni Ahasi, ọmọ Jotamu, jọba ní Juda. +Nígbà tí Ahasi lọ pàdé Tigilati Pileseri ọba, ní Damasku, ó rí pẹpẹ ìrúbọ kan níbẹ̀, ó sì ranṣẹ sí Uraya alufaa pé kí ó mọ irú rẹ̀ gan-an láìsí ìyàtọ̀ kankan. +Ki Ahasi tó dé, Uraya bá mọ irú pẹpẹ ìrúbọ náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Ahasi rán sí i láti Damasku. +Nígbà tí Ahasi pada dé, o rí i pé Uraya ti mọ pẹpẹ ìrúbọ náà; ó lọ sí ìdí rẹ̀, +ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ lórí rẹ̀. Ó rú ẹbọ ohun mímu, ó sì da ẹ̀jẹ̀ ẹbọ alaafia rẹ̀ sí ara rẹ̀. +Pẹpẹ idẹ tí a ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA wà ní ààrin pẹpẹ tirẹ̀ ati ilé OLUWA. Nítorí náà, Ahasi gbé pẹpẹ idẹ náà sí apá òkè pẹpẹ tirẹ̀. +Lẹ́yìn náà ó pàṣẹ fún Uraya alufaa, ó ní, “Máa lo pẹpẹ ìrúbọ tí ó tóbi yìí fún ẹbọ sísun àárọ̀ ati ẹbọ ohun jíjẹ ìrọ̀lẹ́, ati fún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọba, ati fún ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu ti àwọn eniyan. Kí o sì máa da ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá pa fún ìrúbọ sí orí rẹ̀. Ṣugbọn gbé pẹpẹ ìrúbọ idẹ tọ̀hún sọ́tọ̀ fún mi kí n lè máa lò ó láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ OLUWA.” +Uraya sì ṣe bí Ahasi ọba ti pa á láṣẹ fún un. +Ahasi gé àwọn ẹsẹ̀ idẹ ti agbada ńlá, ó gbé agbada náà kúrò. Ó tún gbé agbada omi ńlá tí a fi idẹ ṣe, tí wọ́n gbé ka ẹ̀yìn àwọn akọ mààlúù idẹ mejila, ó sì gbé e lé orí ìpìlẹ̀ tí a fi òkúta ṣe. +Nítorí pé Ahasi fẹ́ tẹ́ ọba Asiria lọ́rùn, ó gbé pátákó tí wọ́n tẹ́ fún ìtẹ́ ọba kúrò, ó sì sọ ibẹ̀ dí ẹnu ọ̀nà tí ọba ń gbà wọ ilé OLUWA. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasi ọba ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. +Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun. Kò tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere Dafidi baba ńlá rẹ̀, ṣugbọn ó ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, +Ahasi kú, wọn sì sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi, Hesekaya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +nípa títẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọba Israẹli. Òun náà tilẹ̀ fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun sí oriṣa gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè oníwà burúkú tí OLUWA lé kúrò lórí ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Israẹli. +Ní gbogbo ibi gíga, ati àwọn orí òkè ati abẹ́ gbogbo igi ni Ahasi tií máa rúbọ, tíí sìí sun turari. +Resini, ọba Siria, ati Peka, ọba Israẹli, gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dó ti Ahasi, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀. +Ní àkókò kan náà ni ọba Edomu gba Elati pada, ó sì lé àwọn ará Juda tí wọn ń gbé ibẹ̀, àwọn ará Edomu sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní olónìí. +Ahasi ranṣẹ lọ bá Tigilati Pileseri, ọba Asiria, ó ní, “Iranṣẹ ati ọmọ rẹ ni mo jẹ́, nítorí náà, jọ̀wọ́ wá gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọba Siria ati ti Israẹli tí wọ́n gbógun tì mí.” +Ahasi kó fadaka ati wúrà tí ó wà ninu ilé OLUWA, ati tinú àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin jọ, ó kó o ranṣẹ sí ọba Asiria. +Ọba Asiria gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì gbógun ti Damasku, ó ṣẹgun rẹ̀, ó pa Resini ọba, ó sì kó gbogbo àwọn eniyan ìlú náà lẹ́rú lọ sí Kiri. +Ahasi, Ọba Juda. +Ní ọdún kejila tí Ahasi jọba ní Juda, ni Hoṣea ọmọ Ela jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì jọba fún ọdún mẹsan-an. +Wọ́n gbé àwọn òpó tí a fi òkúta ṣe ati àwọn ère Aṣerimu sí orí àwọn òkè ati sí abẹ́ àwọn igi tí wọ́n ní ìbòòji. +Wọ́n ń sun turari ní gbogbo orí òkè, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn tí OLUWA lé jáde kúrò ní ilẹ̀ náà. Wọ́n mú kí ibinu OLUWA ru pẹlu ìwà burúkú wọn, +wọ́n sì lòdì sí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn pé wọn kó gbọdọ̀ bọ oriṣa. +Sibẹ, OLUWA ń rán àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati àwọn wolii rẹ̀ kí wọ́n máa kìlọ̀ fún Israẹli ati Juda pé, “Ẹ kọ ọ̀nà burúkú yín sílẹ̀ kí ẹ sì pa òfin ati ìlànà mi, tí mo fún àwọn baba ńlá yín mọ́; àní àwọn tí mo fun yín nípasẹ̀ àwọn wolii, iranṣẹ mi.” +Ṣugbọn wọn kò gbọ́, wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn líle bí àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò gba OLUWA Ọlọrun wọn gbọ́. +Wọ́n kọ ìlànà rẹ̀, wọn kò pa majẹmu tí ó bá àwọn baba ńlá wọn dá mọ́, wọn kò sì fetí sí àwọn ìkìlọ̀ rẹ̀. Wọ́n ń sin oriṣa lásánlàsàn, àwọn pàápàá sì di eniyan lásán. Wọ́n tẹ̀ sí ìwà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká; wọ́n kọ òfin tí OLUWA ṣe fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà wọn. +Wọ́n rú gbogbo òfin OLUWA Ọlọrun wọn; wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù meji, wọ́n ń sìn wọ́n. Wọ́n gbẹ́ ère oriṣa Aṣera, wọ́n sì ń bọ àwọn ohun tí ó wà lójú ọ̀run ati oriṣa Baali. +Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn rú ẹbọ sísun sí oriṣa, wọ́n ń ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn alásọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì fi ara wọn jì láti ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n sì fi bẹ́ẹ̀ rú ibinu rẹ̀ sókè. +Nítorí náà, OLUWA bínú sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì run wọ́n kúrò níwájú rẹ̀, ṣugbọn ó fi Juda nìkan sílẹ̀. +Sibẹ, àwọn ará Juda kò pa òfin OLUWA Ọlọrun wọn mọ́, wọ́n tẹ̀lé ìwà tí àwọn ọmọ Israẹli ń hù. +Ó ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò tó ti àwọn ọba tí wọ́n jẹ ṣáájú rẹ̀. +OLUWA bá kọ gbogbo àwọn ìran Israẹli sílẹ̀, ó jẹ wọ́n níyà, ó sì fi wọ́n lé àwọn apanirun lọ́wọ́ títí wọ́n fi pa wọn run níwájú rẹ̀. +Lẹ́yìn tí OLUWA ti fi ìyapa sí ààrin Israẹli ati ìdílé Dafidi, Israẹli fi Jeroboamu ọmọ Nebati jọba. Jeroboamu mú kí wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, ó sì mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ ńlá. +Àwọn ọmọ Israẹli ń tẹ̀lé gbogbo ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, wọn kò sì yipada kúrò ninu wọn, +títí tí OLUWA fi run wọ́n kúrò níwájú rẹ̀, bí ó ti kìlọ̀ fún wọn láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Asiria ṣe kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Asiria, níbi tí wọ́n wà títí di òní olónìí. +Ọba Asiria kó àwọn eniyan láti Babiloni, Kuta, Afa, Hamati ati Sefafaimu, ó kó wọn dà sinu àwọn ìlú Samaria dípò àwọn ọmọ Israẹli tí ó kó lọ. Wọ́n gba ilẹ̀ Samaria, wọ́n sì ń gbé inú àwọn ìlú rẹ̀. +Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ dé ibẹ̀, wọn kò bẹ̀rù OLUWA, nítorí náà OLUWA rán àwọn kinniun sí ààrin wọn, wọ́n sì pa ninu àwọn eniyan tí ọba Asiria kó wá. +Wọ́n bá lọ ròyìn fún ọba Asiria pé àwọn eniyan tí ó kó lọ sí ilẹ̀ Samaria kò mọ òfin Ọlọrun ilẹ̀ náà, nítorí náà ni Ọlọrun ṣe rán kinniun tí ó ń pa wọ́n. +Ọba bá pàṣẹ, ó ní, “Ẹ dá ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí a kó lẹ́rú pada sí Samaria, kí ó lè kọ́ àwọn eniyan náà ní òfin Ọlọrun ilẹ̀ náà.” +Nítorí náà, ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí wọ́n kó wá láti Samaria pada lọ, ó sì ń gbé Bẹtẹli, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn eniyan náà bí wọn yóo ṣe máa sin OLUWA. +Ṣugbọn àwọn oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè tí ń gbé Samaria ṣì ń gbẹ́ ère oriṣa wọn, wọ́n fi wọ́n sinu àwọn ilé oriṣa tí àwọn ọmọ Israẹli ti kọ́. Olukuluku wọn ṣe oriṣa tirẹ̀ sí ibi tí ó ń gbé. +Ṣalimaneseri Ọba Asiria gbógun tì í; Hoṣea bá jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún un, ó sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un ní ọdọọdún. +Àwọn ará Babiloni gbẹ́ ère oriṣa Sukotu Benoti, àwọn ará Kuti gbẹ́ ère oriṣa Negali, àwọn ará Hamati gbẹ́ ère oriṣa Aṣima, +àwọn ará Afa gbẹ́ ère oriṣa Nibihasi ati Tataki, àwọn ará Sefafaimu sì ń sun ọmọ wọn ninu iná fún Adirameleki ati Anameleki, àwọn oriṣa wọn. +Àwọn eniyan náà bẹ̀rù OLUWA pẹlu, wọ́n sì yan oniruuru eniyan lára wọn, láti máa ṣe alufaa níbi àwọn pẹpẹ oriṣa gíga, láti máa bá wọn rúbọ níbẹ̀. +Wọ́n ń sin OLUWA, ṣugbọn wọ́n tún ń bọ àwọn oriṣa tí wọn ń bọ tẹ́lẹ̀ ní orílẹ̀-èdè tí olukuluku wọ́n ti wá. +Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń ṣe títí di òní olónìí. Wọn kò bẹ̀rù OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, tabi àṣẹ tí ó pa, tabi òfin tí ó ṣe fún àwọn ọmọ Jakọbu, tí ó sọ ní Israẹli. +OLUWA bá wọn dá majẹmu, ó sì pàṣẹ fún wọn, pé, wọn kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, tabi kí wọ́n júbà wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tabi kí wọ́n rúbọ sí wọn; +ṣugbọn wọ́n gbọdọ̀ bẹ̀rù OLUWA tí ó mú wọn jáde kúrò ní Ijipti pẹlu ọwọ́ agbára ńlá ati ipá. Ó ní kí wọ́n máa tẹríba fún un, kí wọn sì máa rúbọ sí i. +Ó ní wọ́n gbọdọ̀ pa àwọn ìlànà, àṣẹ ati òfin tí ó kọ sílẹ̀ fún wọn mọ́. Wọn kò gbọdọ̀ bẹ̀rù àwọn oriṣa, +wọn kò sì gbọdọ̀ gbàgbé majẹmu tí òun bá wọn dá. Wọn kò gbọdọ̀ bẹ̀rù àwọn oriṣa, +ṣugbọn kí wọn bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun wọn, yóo sì gbà wọ́n lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn. +Ṣugbọn ní ọdún kan, Hoṣea ranṣẹ sí So, ���ba Ijipti pé, kí ó ran òun lọ́wọ́, kò sì san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Asiria mọ́. Nígbà tí Ṣalimaneseri gbọ́, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ju Hoṣea sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. +Ṣugbọn àwọn eniyan náà kò gbọ́, wọ́n sì ń tẹ̀lé ìwà àtijọ́ wọn. +Àwọn eniyan ilẹ̀ náà sin OLUWA, ṣugbọn wọ́n ń bọ àwọn ère tí wọ́n gbẹ́ pẹlu. Àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ wọn sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ títí di òní olónìí. +Lẹ́yìn náà, Ṣalimaneseri, ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ Israẹli, ó dó ti Samaria fún ọdún mẹta. +Ní ọdún kẹsan-an tí Hoṣea jọba, ọba Asiria ṣẹgun Samaria, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbèkùn lọ sí Asiria. Ó kó wọn sí ìlú Hala ati sí etí odò Habori tí ó wà ní agbègbè Gosani, ati sí àwọn ìlú Media. +Ogun kó Samaria nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wọn ó gbà wọ́n lọ́wọ́ ọba Farao, tí ó sì kó wọn jáde kúrò ní Ijipti. Wọ́n ti bọ oriṣa, +wọ́n sì tẹ̀lé ìwà àwọn eniyan tí OLUWA lé jáde kúrò fún wọn, ati àwọn àṣàkaṣà tí àwọn ọba Israẹli kó wá. +Àwọn ọmọ Israẹli ṣe oríṣìíríṣìí nǹkan níkọ̀kọ̀, tí OLUWA Ọlọrun wọn kò fẹ́. Wọ́n kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ sinu àwọn ìlú wọn: wọ́n kọ́ sinu ilé ìṣọ́, títí kan àwọn ìlú olódi. +Hoṣea Ọba Israẹli. +Ní ọdún kẹta tí Hoṣea, ọmọ Ela, jọba ní Israẹli ni Hesekaya, ọmọ Ahasi jọba ní Juda. +Nígbà tí ó ti di ọdún kẹta tí ó ti dó ti Samaria, ó ṣẹgun rẹ̀. Èyí jẹ́ ọdún kẹfa tí Hesekaya jọba, ati ọdún kẹsan-an tí Hoṣea jọba. +Ọba Asiria kó àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbèkùn lọ sí Asiria, ó sì kó wọn sí ìlú Hala ati Habori tí ó wà ní agbègbè odò Gosani ati sí àwọn ìlú àwọn ará Media. +Ogun kó Samaria nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli kò pa òfin OLUWA Ọlọrun wọn mọ́, wọ́n si da majẹmu tí OLUWA bá wọn dá. Wọn kò pa àwọn òfin tí OLUWA fún Mose, iranṣẹ rẹ̀ mọ́, wọn kò sì gbọ́ràn. +Ní ọdún kẹrinla tí Hesekaya jọba ní Juda, ni Senakeribu, ọba Asiria, gbógun ti àwọn ìlú olódi Juda, ó sì ṣẹgun wọn. +Hesekaya ranṣẹ sí Senakeribu, ọba Asiria, tí ó wà ní Lakiṣi nígbà náà, ó ní: “Mo ti ṣẹ̀, jọ̀wọ́ dá ọwọ́ ogun rẹ dúró; n óo sì san ohunkohun tí o bá bèèrè.” Ọba náà sì bèèrè fún ọọdunrun ìwọ̀n talẹnti fadaka ati ọgbọ̀n ìwọ̀n talẹnti wúrà lọ́wọ́ Hesekaya ọba Juda. +Hesekaya bá kó gbogbo fadaka tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ti inú ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ranṣẹ sí i. +Ó sì ṣí wúrà tí ó wà lára ìlẹ̀kùn ilé OLUWA ati wúrà tí òun tìkararẹ̀ fi bo àwọn òpó ìlẹ̀kùn, ó kó wọn ranṣẹ sí Senakeribu. +Ọba Asiria rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀: Tatani, Rabusarisi ati Rabuṣake pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun láti Lakiṣi láti gbógun ti Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu wọ́n dúró sí ibi ọ̀nà tí àwọn tí wọn ń hun aṣọ tí ń ṣiṣẹ́, lẹ́bàá kòtò omi tí ń ṣàn wá láti adágún omi tí ó wà ninu ìlú lápá òkè. +Nígbà tí wọ́n ké sí Hesekaya ọba, Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó ń ṣe àkóso ààfin, ati Ṣebina akọ̀wé ọba, ati Joa ọmọ Asafu, tí ń ṣe àkóso ìwé ìrántí ni wọ́n jáde sí wọn. +Rabuṣake ní, “Ẹ sọ fún Hesekaya pé, ọba ńlá, ọba ilẹ̀ Asiria ní kí ni ó gbẹ́kẹ̀lé? +Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkandinlọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Abi, ọmọ Sakaraya. +Ṣé ó rò pé ọ̀rọ̀ lásán lè dípò ọgbọ́n ati agbára ogun ni? Ó ní, ta ni Hesekaya gbẹ́kẹ̀lé tí ó fi ń dìtẹ̀ mọ́ òun? +Ṣé Ijipti ni ó gbójú lé pé yóo ran òun lọ́wọ́? Ó ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí ẹni tí ó ń fi igi tí kò ní agbára ṣe ọ̀pá ìtilẹ̀. Tí igi náà bá dá, yóo gún un lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ijipti rí sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ wọn lé e. +“Ṣugbọn tí ẹ bá sọ fún mi pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun yín, ṣebí àwọn ibi ìrúbọ ati àwọn pẹpẹ Ọlọrun náà ni Hesekaya ti bàjẹ́, tí ó sì sọ fún àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu pé, ‘Níwájú pẹpẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu nìkan ni kí ẹ ti máa sìn.’ +Nisinsinyii, ẹ wá ṣe àdéhùn pẹlu ọba Asiria, oluwa mi. N óo fun yín ní ẹgbaa (2,000) ẹṣin bí ẹ bá lè rí ẹgbaa (2,000) eniyan tí yóo gùn wọ́n. +Ẹ kò lè ṣẹgun ẹni tí ó kéré jùlọ ninu àwọn ọ̀gágun ọba Asiria, sibẹ o rò pé àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ọba Ijipti yóo ràn ọ́ lọ́wọ́. +Ṣé o rò pé lásán ni mo wá láti pa ilẹ̀ yìí run, láìsí ìrànlọ́wọ́ OLUWA? OLUWA fúnra rẹ̀ ni ó sọ fún mi pé kí n wá pa ilẹ̀ yìí run.” +Nígbà náà ni Eliakimu, ọmọ Hilikaya ati Ṣebina ati Joa sọ fún Rabuṣake pé, “Jọ̀wọ́, bá àwa iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Aramaiki nítorí pé a gbọ́. Má sọ èdè Heberu mọ́, nítorí pé àwọn tí wọ́n wà lórí odi ń gbọ́ ohun tí ò ń sọ.” +Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò pé ẹ̀yin ati ọba nìkan ni ọba Asiria rán mi sí ni? Rárá, àwọn tí wọ́n wà lórí odi náà wà lára àwọn tí mò ń bá sọ̀rọ̀. Àwọn náà yóo jẹ ìgbẹ́ ara wọn tí wọn yóo sì mu ìtọ̀ ara wọn bí ẹ̀yin náà.” +Nígbà náà ni Rabuṣake kígbe sókè rara ní èdè Heberu tíí ṣe èdè àwọn ará Juda ó ní, “Ẹ gbọ́ ohun tí ọba Asiria ń sọ fun yín; +ó ní òun ń kìlọ̀ fun yín pé kí ẹ má jẹ́ kí Hesekaya tàn yín jẹ, kò lè gbà yín sílẹ̀. +Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, nítorí pé ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ Dafidi, baba ńlá rẹ̀. +Ó ní kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ó mú ki ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA kí ó máa sọ pé OLUWA yóo gbà yín sílẹ̀, ati pé kò ní jẹ́ kí ogun Asiria kó ìlú yín. +Ẹ má ṣe gbọ́ ti Hesekaya; nítorí pé ọba Asiria ní kí ẹ jáde wá kí ẹ bá òun ṣe àdéhùn alaafia; òun yóo gbà yín láàyè láti máa jẹ èso àjàrà ninu ọgbà àjàrà yín. Ẹ óo máa jẹ èso orí igi ọ̀pọ̀tọ́ yín, ẹ óo sì máa mu omi láti inú kànga yín; +títí di ìgbà tí òun óo fi ko yín lọ sí ilẹ̀ mìíràn tí yóo dàbí tiyín, ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati waini, ilẹ̀ tí ó kún fún oúnjẹ ati ọgbà àjàrà, ilẹ̀ tí ó kún fún igi olifi ati oyin, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ má baà kú. Ẹ má jẹ́ kí Hesekaya tàn yín, kí ẹ máa rò pé OLUWA yóo gbà yín. +Ṣé ọlọrun àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn gbà wọ́n lọ́wọ́ ọba Asiria? +Níbo ni ọlọrun Hamati ati ti Aripadi wà? Níbo ni àwọn ọlọrun Sefafaimu, ati ti Hena ati ti Ifa wà? Ṣé wọ́n gba Samaria lọ́wọ́ mi? +Nígbà wo ni ọ̀kan ninu àwọn ọlọrun orílẹ̀-èdè wọnyi gba orílẹ̀-èdè wọn lọ́wọ́ ọba Asiria rí, tí OLUWA yóo fi gba Jerusalẹmu lọ́wọ́ mi?” +Àwọn eniyan náà dákẹ́ jẹ́ẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba Hesekaya ti pàṣẹ fún wọn, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kankan. +Nígbà náà ni Eliakimu, tí ń ṣe àkóso ààfin ati Ṣebina, akọ̀wé ọba, ati Joa, tí ń ṣe àkóso ìwé ìrántí fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, wọ́n sì lọ sọ ohun tí olórí ogun náà wí fun ọba. +Ó wó gbogbo àwọn pẹpẹ oriṣa, ó wó gbogbo àwọn òpó tí wọ́n fi òkúta ṣe, ó sì gé gbogbo àwọn ère oriṣa Aṣera. Ó rún ejò idẹ tí Mose ṣe, tí wọn ń pè ní Nehuṣitani nítorí pé títí di àkókò náà àwọn ọmọ Israẹli a máa sun turari sí i. +Hesekaya ní igbagbọ ninu OLUWA Ọlọrun Israẹli. Juda kò sì ní ọba mìíràn tí ó dà bíi rẹ̀, yálà ṣáájú rẹ̀ ni, tabi lẹ́yìn rẹ̀. +Ó jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA, kò yapa kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣugbọn ó fi tọkàntọkàn pa àwọn òfin tí OLUWA fún Mose mọ́. +OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó ń ṣe. Ó gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria, ó di òmìnira, ó kọ̀ kò sìn ín mọ́. +Ó ṣẹgun àwọn ará Filistia, títí dé ìlú Gasa ati agbègbè tí ó yí i ká, ati ilé ìṣọ́ wọn, ati ìlú olódi wọn. +Ní ọdún kẹrin tíí Hesekaya jọba, tíi ṣe ọdún keje tí Hoṣea, ọmọ Ela, jọba lórí Israẹli, Ṣalimaneseri, ọba Asiria, gbógun ti Samaria, ó sì dó tì í. +Hesekaya, Ọba Juda. +Nígbà tí Hesekaya ọba gbọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó bá lọ sinu ilé OLUWA. +“Má jẹ́ kí Ọlọrun tí o gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ pé ọba Asiria kò ní fi ogun kó Jerusalẹmu. +O ti gbọ́ ìròyìn ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn tí ó ti bá jagun, pé ó pa wọ́n run patapata ni. Ṣé ìwọ rò pé o lè là? +Àwọn baba ńlá mi ti pa àwọn ìlú Gosani, Harani, Resefu ati àwọn ọmọ Edẹni tí wọ́n wà ní Telasari run, àwọn ọlọrun wọn kò sì lè gbà wọ́n. +Níbo ni ọba Hamati, ati ti Aripadi, ati ti Sefafaimu, ati ti Hena, ati ti Ifa wà?” +Hesekaya ọba gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn iranṣẹ, ó kà á. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé OLUWA, ó tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA. +Ó gbadura pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ń gbé láàrin àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun tí ń jọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, ìwọ ni o dá ayé ati ọ̀run. +Nisinsinyii, bojú wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa; kí o sì gbọ́ bí Senakeribu ti ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ìwọ Ọlọrun alààyè. +OLUWA, àwa mọ̀ pé ní òtítọ́ ni ọba Asiria ti pa ọpọlọpọ àwọn orílẹ̀-èdè run, ó sì ti sọ ilẹ̀ wọn di aṣálẹ̀. +Ó ti dáná sun àwọn ọlọrun wọn; ṣugbọn wọn kì í ṣe Ọlọrun tòótọ́, ère lásán tí a fi igi ati òkúta gbẹ́ ni wọ́n, iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ eniyan. +Nisinsinyii OLUWA Ọlọrun wa, jọ̀wọ́ gbà wá lọ́wọ́ Asiria kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA nìkan ni ỌLỌRUN.” +Ó rán Eliakimu ati Ṣebina ati àwọn àgbààgbà alufaa, tí wọ́n fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara wọn, lọ sọ́dọ̀ wolii Aisaya ọmọ Amosi. +Nígbà náà ni Aisaya ọmọ Amosi ranṣẹ sí Hesekaya ọba pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Mo ti gbọ́ adura rẹ nípa Senakeribu, ọba Asiria. +Ohun tí OLUWA sọ nípa Senakeribu ni pé,‘Sioni yóo fi ojú tẹmbẹlu rẹ,yóo sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà;Jerusalẹmu yóo fi ọ́ rẹ́rìn-ín.’ +Ta ni o rò pé ò ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí,tí o sì fi ń ṣe ẹlẹ́yà?Ta ni ò ń kígbe mọ́,tí o sì ń wò ní ìwò ìgbéraga?Èmi Ẹni Mímọ́ Israẹli ni! +O rán oníṣẹ́ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà,o ní, ‘N óo fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi ṣẹgun àwọn òkè,títí dé òkè tí ó ga jùlọ ní Lẹbanoni;mo gé àwọn igi Kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,ati àwọn igi sipirẹsi rẹ̀ tí ó dára jùlọ,Mo wọ inú igbó rẹ̀ tí ó jìnnà ju lọ,mo sì wọ inú aṣálẹ̀ rẹ̀ tí ó dí jùlọ. +Mo gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì,mo sì mu omi rẹ̀;ẹsẹ̀ àwọn jagunjagun mi ni ó sì gbẹ́ àwọn odò Ijipti.’ +“Ṣé o kò mọ̀ péó pẹ́ tí mo ti pinnu àwọn nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ wọnyi ni?Èmi ni mo fún ọ ní agbáratí o fi sọ àwọn ìlú olódi di òkítì àlàpà. +Nítorí náà ni àwọn tí wọn ń gbé inú àwọn ìlú olódi náà ṣe di aláìlágbára,tí ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.Wọ́n dàbí ìgbà tí atẹ́gùn gbígbóná ìlà oòrùnbá fẹ́ lu koríko tabi ewéko tí ó hù ní orí òrùlé. +Ṣugbọn kò sí ohun tí n kò mọ̀ nípa rẹ,mo mọ àtijókòó rẹ, àtijáde rẹati àtiwọlé rẹ, ati bí o ti ń ta kò mí. +Mo ti gbọ́ ìròyìn ibinu rẹ ati ìgbéraga rẹ,n óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú, n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ lẹ́nu,n óo sì fà ọ́ pada sí ibi tí o ti wá.” +Nígbà náà ni Aisaya sọ fún Hesekaya ọba pé, “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nípa àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ nìyí. Ní ọdún yìí ati ọdún tí ń bọ̀, ẹ óo jẹ àjàrà tí ó lalẹ̀ hù, ṣugbọn ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ẹ óo le gbin ohun ọ̀gbìn yín, ẹ óo sì kórè rẹ̀, ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì jẹ èso àjàrà rẹ̀. +Wọ́n sì jíṣẹ́ Hesekaya ọba fún Aisaya pé, “Ọba sọ pé òní jẹ́ ọjọ́ ìrora, wọ́n ń fi ìyà jẹ wá, a sì wà ninu ìtìjú. A dàbí aboyún tí ó fẹ́ bímọ ṣugbọn tí kò ní agbára tó. +Yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda. Wọn yóo dàbí irúgbìn tí gbòǹgbò rẹ̀ wọnú ilẹ̀ lọ tí ó sì ń so èso jáde. +Àwọn eniyan yóo là ní Jerusalẹmu, àwọn eniyan yóo sì ṣẹ́kù ni Òkè Sioni, nítorí pé ìtara ni OLUWA yóo fi ṣe é. +“Ohun tí OLUWA sọ nípa ọba Asiria ni pé, kò ní wọ inú ìlú yìí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ta ọfà kankan sí i. Kò sí ọmọ ogun kan tí ó ní apata tí yóo wá sí ẹ̀bá ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni kò ní lè gbìyànjú láti gbógun tì í. +Ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóo gbà lọ láìwọ ìlú yìí nítorí èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +N óo gbèjà ìlú yìí, n óo sì dáàbò bò ọ́ nítorí ògo mi ati ìlérí tí mo ti ṣe fún Dafidi iranṣẹ mi.” +Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni angẹli OLUWA lọ sí ibùdó ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an lé ẹẹdẹgbaata (185,000) àwọn ọmọ ogun, wọn kú kí ilẹ̀ ọjọ́ keji tó mọ́. +Senakeribu ọba Asiria bá pada sí Ninefe. +Ní ọjọ́ kan níbi tí ó ti ń bọ oriṣa ninu ilé Nisiroku, oriṣa rẹ̀, ni Adirameleki ati Ṣareseri, àwọn ọmọ rẹ̀ bá fi idà pa á, wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Ararati. Esaradoni ọmọ rẹ̀ bá jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ọba Asiria ti rán Rabuṣake, olórí ogun rẹ̀ kan, láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí Ọlọrun alààyè. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn yìí, kí ó sì jẹ àwọn tí wọ́n sọ ọ́ níyà. Nítorí náà, gbadura fún àwọn eniyan wa tí wọ́n kù.” +Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ ọba fún Aisaya tán, +ó ranṣẹ pada ó ní, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé OLUWA ní kí ó má jẹ́ kí iṣẹ́ tí ọba Asiria rán sí i pé OLUWA kò lè gbà á dẹ́rùbà á. +Ó ní òun óo fi ẹ̀mí kan sinu rẹ̀, tí yóo mú kí ó sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nígbà tí ó bá gbọ́ ìròyìn kan, òun óo sì jẹ́ kí wọ́n pa á nígbà tí ó bá dé ilẹ̀ rẹ̀.” +Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi láti lọ jagun ní Libina, ó sì lọ sibẹ láti lọ rí i. +Nígbà tí ọba Asiria gbọ́ pé Tirihaka, ọba Etiopia, ń kó ogun rẹ̀ bọ̀ láti bá òun jagun, ó ranṣẹ sí Hesekaya, ọba Juda, ó ní kí wọ́n sọ fún un pé, +Ọba Bèèrè Ìmọ̀ràn Lọ́wọ́ Aisaya. +Nígbà tí àkókò tó fún OLUWA láti fi ààjà gbé Elija lọ sí ọ̀run, Elija ati Eliṣa kúrò ní Giligali. +Elija dáhùn pé, “Ohun tí o bèèrè yìí ṣòro, ṣugbọn bí o bá rí mi nígbà tí wọ́n bá ń gbé mi lọ, o óo rí ohun tí o bèèrè gbà. Ṣugbọn bí o kò bá rí mi, o kò ní rí i gbà.” +Bí wọ́n ti ń lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀, lójijì kẹ̀kẹ́-ogun iná ati ẹṣin iná gba ààrin wọn kọjá, Elija sì bá ààjà gòkè lọ sí ọ̀run. +Bí Eliṣa ti rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó kígbe pe Elija, ó ní, “Baba mi, baba mi, kẹ̀kẹ́-ogun Israẹli ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.” Kò rí Elija mọ́, ó bá fa aṣọ rẹ̀ ya sí meji láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. +Lẹ́yìn náà ó mú aṣọ àwọ̀lékè Elija tí ó bọ́ sílẹ̀, ó sì pada lọ dúró ní etí odò Jọdani. +Ó fi aṣọ àwọ̀lékè tí ó já bọ́ sílẹ̀ lára Elija lu odò, ó sì kígbe pé, “Níbo ni OLUWA Ọlọrun Elija wà?” Lẹ́yìn náà odò pín sí meji, Eliṣa bá kọjá sí òdìkejì. +Nígbà tí àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọ́n wà ní Jẹriko rí i, wọ́n ní, “Ẹ̀mí Elija ti wà lára Eliṣa!” Wọ́n lọ pàdé rẹ̀, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀, +wọ́n ní, “Aadọta ọkunrin alágbára wà pẹlu àwa iranṣẹ rẹ, jọ́wọ́ jẹ́ kí wọ́n lọ wá ọ̀gá rẹ, bóyá Ẹ̀mí OLUWA tí ó gbé e lọ ti jù ú sílẹ̀ ní orí ọ̀kan ninu àwọn òkè agbègbè yìí, tabi ninu àfonífojì kan.”Eliṣa sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe rán wọn lọ.” +Ṣugbọn wọ́n rọ̀ ọ́ títí tí ojú fi ń tì í, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ rán wọn lọ.” Wọ́n bá rán àwọn aadọta ọkunrin lọ, wọ́n wá Elija ní àwọn orí òkè ati àwọn àfonífojì fún ọjọ́ mẹta, ṣugbọn wọn kò rí i. +Wọ́n pada wá jábọ̀ fún Eliṣa ní Jẹriko, ó sì wí fún wọn pé, “Ṣebí mo ti sọ fun yín pé kí ẹ má lọ?” +Àwọn ọkunrin ìlú náà wá sọ́dọ̀ Eliṣa, wọ́n sọ fún un pé, “Ìlú yìí dára gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti mọ̀, ṣugbọn omi tí à ń mu kò dára, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ náà sì jẹ́ aṣálẹ̀.” +Elija sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín nítorí pé OLUWA rán mi sí Bẹtẹli.”Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Bẹtẹli. +Eliṣa bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bu iyọ̀ sinu abọ́ tuntun, kí ẹ sì gbé e wá fún mi.” Wọ́n bá ṣe bí ó ti wí. +Lẹ́yìn náà, ó jáde lọ sí ibi orísun omi náà, ó da iyọ̀ náà sí i, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA wí, ‘Mo sọ omi yìí di ọ̀tun lónìí, kò ní fa ikú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ba oyún jẹ́ mọ́.’ ” +Láti ìgbà náà ni omi náà ti dára títí di òní olónìí gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọ. +Eliṣa kúrò níbẹ̀, ó lọ sí Bẹtẹli. Bí ó ti ń lọ, àwọn ọmọdekunrin kan ní ìlú náà bẹ̀rẹ̀ sí fi Eliṣa ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n ń wí pé, “Kúrò níbí, ìwọ apárí! Kúrò níbí, ìwọ apárí!” +Nígbà tí ó yí ojú pada, tí ó rí wọn, ó ṣépè lé wọn ní orúkọ OLUWA, abo ẹranko beari meji sì jáde láti inú igbó, wọ́n fa mejilelogoji ninu àwọn ọmọ náà ya. +Eliṣa sì lọ sí òkè Kamẹli, láti ibẹ̀, ó lọ sí Samaria. +Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Bẹtẹli tọ Eliṣa wá, wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?”Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.” +Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín, nítorí pé OLUWA rán mi sí Jẹriko.”Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Jẹriko. +Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Jẹriko tọ Eliṣa wá, wọ́n sì bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?”Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.” +Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín nítorí pé OLUWA rán mi sí odò Jọdani.”Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ ń lọ. +Aadọta ninu àwọn ọmọ àwọn wolii náà sì dúró ní òkèèrè, wọ́n ń wò wọ́n. Elija ati Eliṣa sì dúró létí odò Jọdani. +Elija bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ó fi lu odò náà, odò sì pín sí meji títí tí Elija ati Eliṣa fi kọjá sí òdìkejì odò lórí ìyàngbẹ ilẹ̀. +Níbẹ̀ ni Elija ti bèèrè lọ́wọ́ Eliṣa pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ kí á tó gbé mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.”Eliṣa sì dáhùn pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìlọ́po meji agbára rẹ bà lé mi.” +A Gbé Elija Lọ Sọ́run. +Ní àkókò kan Hesekaya ṣàìsàn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ kú. Wolii Aisaya ọmọ Amosi, wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o palẹ̀ ilé rẹ mọ́ nítorí pé kíkú ni o óo kú, o kò ní yè.” +Hesekaya dáhùn pé, “Ó rọrùn fún òjìji láti lọ siwaju ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá, kí ó pada sẹ́yìn ni mo fẹ́.” +Aisaya gbadura sí OLUWA, OLUWA sì mú kí òjìji pada sẹ́yìn ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá lára àtẹ̀gùn ilé tí ọba Ahasi ṣe. +Ní àkókò kan náà ni Merodaki Baladani, ọmọ Baladani, ọba Babiloni, fi ìwé ati ẹ̀bùn ranṣẹ sí Hesekaya nítorí ó gbọ́ pé Hesekaya ń ṣe àìsàn. +Hesekaya gba àwọn oníṣẹ́ náà ní àlejò. Ó fi gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀, fadaka, wúrà, turari, òróró iyebíye ati gbogbo ohun ìjà rẹ̀ hàn wọ́n. Kò sí ohun kan ninu ilé ìṣúra rẹ̀ ati ní gbogbo ìjọba rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n. +Nígbà náà ni wolii Aisaya lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekaya, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin wọnyi ti wá, kí ni wọ́n sì sọ fún ọ?”Hesekaya dáhùn pé, “Ọ̀nà jíjìn ni wọ́n ti wá, láti Babiloni.” +Aisaya bá tún bèèrè pé, “Kí ni wọ́n rí ninu ààfin rẹ?”Ọba dáhùn, ó ní, “Kò sí ohun kan ninu ilé ìṣúra tí n kò fi hàn wọ́n.” +Nígbà náà ni Aisaya sọ fún ọba pé, “OLUWA ní, +‘Àkókò kan ń bọ̀ tí wọn yóo kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ààfin rẹ lọ sí Babiloni, gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ látẹ̀yìnwá títí di òní ni wọn óo kó lọ, wọn kò ní fi nǹkankan sílẹ̀. +Wọn yóo kó ninu àwọn ọmọ rẹ lọ fi ṣe ìwẹ̀fà ní ààfin ọba Babiloni.’ ” +Hesekaya sọ fún Aisaya pé, “Ọ̀rọ̀ OLUWA tí o sọ dára.” Nítorí ó wí ninu ara rẹ̀ pé, alaafia ati ìfọ̀kànbalẹ̀ yóo sá wà ní àkókò tòun. +Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní, +Gbogbo nǹkan yòókù tí Hesekaya ṣe, ìwà akọni rẹ̀ ati bí ó ti ṣe adágún omi ati ọ̀nà omi wọ inú ìlú ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. +Hesekaya kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀; Manase ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +“Mo bẹ̀ ọ́ OLUWA, ranti bí mo ti sìn ọ́ pẹlu òtítọ́ ati ọkàn pípé, ati bí mo ti ń ṣe ohun tí o fẹ́.” Ó sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. +Aisaya jáde kúrò lọ́dọ̀ ọba, ṣugbọn kí ó tó jáde kúrò ní àgbàlá ààfin, OLUWA sọ fún un pé, +“Pada lọ sọ́dọ̀ Hesekaya, olórí àwọn eniyan mi, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀, mo sì ti rí omijé rẹ̀. N óo wò ó sàn, ní ọjọ́ kẹta, yóo lọ sí ilé OLUWA, +n óo sì jẹ́ kí ó gbé ọdún mẹẹdogun sí i. N óo gba òun ati Jerusalẹmu lọ́wọ́ ọba Asiria. N óo sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí tèmi fúnra mi ati nítorí ìlérí tí mo ṣe fún Dafidi, iranṣẹ mi.’ ” +Aisaya bá sọ fún àwọn iranṣẹ ọba pé kí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ sí orí oówo rẹ̀, kí ara rẹ̀ lè dá. +Hesekaya ọba bèèrè pé, “Kí ni yóo jẹ́ àmì pé OLUWA yóo wò mí sàn, ati pé n óo lọ sí ilé OLUWA ní ọjọ́ kẹta?” +Aisaya dáhùn pé, “OLUWA yóo fún ọ ní àmì láti fihàn pé òun yóo mú ìlérí òun ṣẹ. Èwo ni o fẹ́, ninu kí òjìji lọ siwaju ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá tabi kí ó pada sẹ́yìn ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá?” +Àìsàn Hesekaya Ọba, ati Ìwòsàn Rẹ̀. +Ọmọ ọdún mejila ni Manase nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún marundinlọgọta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hefisiba. +OLUWA sọ láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀, pé, +“Manase ọba ti ṣe àwọn ohun ìríra wọnyi, wọ́n burú ju èyí tí àwọn ará Kenaani ṣe lọ. Ó sì mú kí Juda dẹ́ṣẹ̀ nípa pé wọ́n ń bọ àwọn ère rẹ̀. +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní òun óo mú ìparun wá sórí Jerusalẹmu ati Juda, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ ìyàlẹ́nu gidigidi fún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́. +Ó ní òun óo jẹ Jerusalẹmu níyà bí òun ti jẹ Samaria níyà. Ó ní bí òun ti ṣe sí ìdílé Ahabu ati àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun óo gbá àwọn eniyan náà kúrò ní Jerusalẹmu, bí àwo tí a nù tí a sì da ojú rẹ̀ bolẹ̀. +OLUWA ní òun óo kọ àwọn eniyan òun yòókù sílẹ̀, òun óo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, ọ̀tá yóo ṣẹgun wọn, wọn yóo sì kó wọn lọ bí ìkógun. +Nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun burúkú l��jú òun, wọ́n sì ti mú òun bínú láti ìgbà tí àwọn baba ńlá wọn ti kúrò ní Ijipti, àní títí di òní olónìí.” +Manase pa ọpọlọpọ àwọn eniyan aláìṣẹ̀ títí tí ẹ̀jẹ̀ fi ń ṣàn ní ìgboro Jerusalẹmu. Ó tún fa àwọn eniyan Juda sinu ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà; nípa bẹ́ẹ̀ ó mú kí wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Manase ṣe ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. +Manase kú, wọ́n sì sin ín sinu ọgba Usa tí ó wà ní ààfin. Amoni ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ẹni ọdún mejilelogun ni Amoni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún meji. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Meṣulemeti ọmọ Harusi ará Jotiba. +Manase ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀lé ìwà ìríra àwọn eniyan ilẹ̀ náà, tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. +Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA bí Manase, baba rẹ̀ ti ṣe. +Ó tẹ̀ sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, ó sì bọ àwọn ère tí baba rẹ̀ bọ. +Ó kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá rẹ̀ sílẹ̀, kò sì júbà àṣẹ rẹ̀. +Àwọn iranṣẹ rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀. +Àwọn eniyan Juda pa àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Amoni ọba, wọ́n sì fi Josaya ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Amoni ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. +Wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì tí ó wà ninu ọgbà Usa ní ààfin. Josaya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ó tún àwọn ilé oriṣa tí Hesekaya, baba rẹ̀ ti parun kọ́, ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ fún oriṣa Baali, ó sì gbẹ́ ère oriṣa Aṣera, bí Ahabu, ọba Israẹli, ti gbẹ́ ẹ. Ó sì ń bọ àwọn ìràwọ̀. +Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ oriṣa sinu ilé OLUWA, níbi tí OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti máa sin òun. +Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ fún àwọn ìràwọ̀ ninu àwọn àgbàlá mejeeji tí wọ́n wà ninu ilé OLUWA. +Ó fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, a máa ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn aláfọ̀ṣẹ, a sì máa ṣe àlúpàyídà. Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ati àwọn abókùúsọ̀rọ̀. Ó hùwà tí ó burú gidigidi níwájú OLUWA, ó sì rú ibinu OLUWA sókè. +Ó gbẹ́ ère Aṣera tí ó gbé sinu ilé OLUWA, ibi tí OLUWA ti sọ fún Dafidi ati Solomoni pé, “Ninu ilé yìí, àní, ní Jerusalẹmu, ni mo yàn láàrin àwọn ìlú àwọn ẹ̀yà mejeejila Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ibi tí ẹ óo ti máa sìn mí títí lae. +Ati pé bí àwọn ọmọ Israẹli bá júbà àṣẹ mi, tí wọ́n pa òfin mi, tí Mose, iranṣẹ mi, fún wọn mọ́, n kò ní jẹ́ kí á lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.” +Ṣugbọn àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda kò júbà OLUWA, Manase sì mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ tí ó burú ju èyí tí àwọn eniyan ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ dá lọ, àní, àwọn tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. +Manase, Ọba Juda. +Ọmọ ọdún mẹjọ ni Josaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanlelọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jedida ọmọ Adaya ará Bosikati. +ati pé Hilikaya fún òun ní ìwé kan; ó sì kà á sí etígbọ̀ọ́ ọba. +Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ìwé náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. +Ó bá pàṣẹ fún Hilikaya alufaa, Ahikamu ọmọ Ṣafani, Akibori ọmọ Mikaya, Ṣafani, akọ̀wé, ati Asaya, iranṣẹ ọba pé, +“Ẹ lọ bèèrè ohun tí a kọ sinu ìwé yìí lọ́wọ́ OLUWA fún èmi ati fún gbogbo eniyan Juda. OLUWA ń bínú sí wa gidigidi nítorí pé àwọn baba ńlá wa kò ṣe ohun tí ìwé yìí pa láṣẹ fún wa.” +Hilikaya alufaa, ati Ahikamu ati Akibori ati Ṣafani ati Asaya bá lọ wádìí lọ́wọ́ wolii obinrin kan tí ń jẹ́ Hulida, tí ń gbé apá keji Jerusalẹmu. Ọkọ rẹ̀ ni Ṣalumu ọmọ Tikifa, ọmọ Harihasi tíí máa ń ṣe ìtọ́jú yàrá tí wọn ń kó aṣọ pamọ́ sí. Wọ́n sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún obinrin náà. +Ó bá rán wọn pada, ó ní: “Ẹ lọ sọ fún ẹni tí ó ran yín sí mi pé, +‘OLUWA ní, “Wò ó n óo jẹ Jerusalẹmu ati àwọn eniyan inú rẹ̀ níyà bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé tí ọba Juda kà. +Nítorí pé wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ń sun turari sí àwọn oriṣa láti mú mi bínú nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Nítorí náà, inú mi yóo ru sí ibí yìí, kò sì ní rọlẹ̀. +Ṣugbọn níti ọba Juda tí ó sọ pé kí ẹ lọ wádìí lọ́wọ́ OLUWA, ẹ sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Nípa ọ̀rọ̀ tí ó ti gbọ́, nítorí pé ó ronupiwada, +ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú OLUWA, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó sì sun ẹkún nígbà tí ó gbọ́ ìlérí ìjìyà tí mo ṣe nípa Jerusalẹmu ati àwọn eniyan ibẹ̀, pé n óo sọ Jerusalẹmu di ahoro ati ibi tí àwọn eniyan yóo máa lo orúkọ rẹ̀ láti gégùn-ún. Ṣugbọn mo ti gbọ́ adura rẹ̀ nítorí pé ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọkún níwájú mi. +Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ó tẹ̀ sí ọ̀nà Dafidi, baba ńlá rẹ̀, kò sì ṣe nǹkankan tí ó lòdì sí àpẹẹrẹ tí Dafidi fi lélẹ̀. +Nítorí náà, n kò ní fi ìyà jẹ Jerusalẹmu nígbà tí ó wà láàyè, n óo jẹ́ kí ó kú ní alaafia.” ’ ”Àwọn ọkunrin náà sì lọ jíṣẹ́ fún Josaya ọba. +Ní ọdún kejidinlogun tí Josaya jọba, ó rán Ṣafani, akọ̀wé rẹ̀, ọmọ Asalaya, ọmọ Meṣulamu, sí ilé OLUWA pé kí ó +lọ sí ọ̀dọ̀ Hilikaya olórí alufaa, kí ó ṣírò iye owó tí àwọn alufaa tí wọ́n wà lẹ́nu ọ̀nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn eniyan, +kí ó gbé owó náà fún àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé OLUWA. Àwọn ni wọn yóo máa san owó fún +àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé ati àwọn agbẹ́kùúta, kí wọ́n sì ra igi ati òkúta tí wọn yóo lò fún àtúnṣe ilé OLUWA. +Ó ní àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé náà kò ní nílò láti ṣe ìṣirò owó tí wọn ń ná, nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́. +Ṣafani jíṣẹ́ ọba fún Hilikaya; Hilikaya olórí alufaa, sì sọ fún un pé òun ti rí ìwé òfin ninu ilé OLUWA. Ó fún Ṣafani ní ìwé náà, ó sì kà á. +Ṣafani bá pada lọ jíṣẹ́ fún ọba, ó sọ fún ọba pé, àwọn iranṣẹ rẹ̀ ti kó owó tí ó wà ninu ilé OLUWA fún àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé OLUWA, +Josaya, Ọba Juda. +Josaya bá pe ìpàdé gbogbo àwọn olórí Juda ati Jerusalẹmu. +Josaya Ọba wó ilé oriṣa Tofeti tí ó wà ní àfonífojì Hinomu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè fi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin rẹ̀ rúbọ sí oriṣa Moleki mọ́. +Ó tú gbogbo ẹṣin tí àwọn ọba Juda ti yà sọ́tọ̀ fún ìsìn oòrùn, ní ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, lẹ́bàá yàrá Natani Meleki, ìwẹ̀fà tí ó wà ní agbègbè ilé OLUWA; ó sì dáná sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ìsìn oòrùn. +Ó wó àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí àwọn ọba Juda kọ́ sórí ilé Ahasi ninu ààfin lulẹ̀, pẹlu àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí Manase kọ́ sinu àwọn àgbàlá meji tí ó wà ninu ilé OLUWA. Ó fọ́ gbogbo wọn túútúú, ó sì kó wọn dà sí àfonífojì Kidironi. +Josaya wó gbogbo ibi gíga tí wọn tún ń pè ní òkè ìdíbàjẹ́, tí Solomoni kọ́ sí apá ìhà ìlà oòrùn Jerusalẹmu, ní ìhà gúsù Òkè Olifi, fún àwọn oriṣa Aṣitoreti, ohun ìríra àwọn ará Sidoni, ati Kemoṣi, ohun ìríra àwọn ará Moabu, ati fún Milikomu, ohun ìríra àwọn ará Amoni. +Josaya ọba fọ́ àwọn òpó òkúta túútúú, ó gé àwọn ère oriṣa Aṣera, ó sì kó egungun eniyan sí ibi tí wọ́n ti hú wọn jáde. +Josaya wó ilé oriṣa tí Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kọ́ sí Bẹtẹli. Josaya wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà níbẹ̀, ó fọ́ òkúta rẹ̀ túútúú, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì jó ère Aṣera pẹlu. +Bí Josaya ti yí ojú pada, ó rí àwọn ibojì kan lórí òkè. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn egungun inú wọn jáde, kí wọ́n sì jó wọn lórí pẹpẹ ìrúbọ náà; ó sì fi bẹ́ẹ̀ sọ pẹpẹ ìrúbọ náà di ìbàjẹ́, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Ọlọrun ti sọ. Nígbà tí Josaya ọba rí ibojì wolii tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà, +ó bèèrè pé, “Ọ̀wọ̀n ibojì ta ni mò ń wò lọ́ọ̀ọ́kán yìí?”Àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli sì dáhùn pé, “Ibojì wolii tí ó wá láti Juda tí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí ò ń ṣe sí pẹpẹ ìrúbọ yìí ni.” +Josaya bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi sílẹ̀ bí ó ti wà, kí wọ́n má ṣe kó egungun rẹ̀.Nítorí náà, wọn kò kó egungun rẹ̀ ati egungun wolii tí ó wá láti Samaria. +Ní gbogbo àwọn ìlú Israẹli ni Josaya ti wó àwọn ilé oriṣa tí àwọn ọba Israẹli kọ́ tí ó bí OLUWA ninu. Bí ó ti ṣe pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní Bẹtẹli ni ó ṣe àwọn pẹpẹ ìrúbọ náà. +Gbogbo wọn lọ sí ilé OLUWA pẹlu àwọn alufaa ati àwọn wolii ati gbogbo àwọn eniyan, àtọmọdé àtàgbà wọn. Ọba bá ka ìwé majẹmu tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA sí etígbọ̀ọ́ wọn. +Ó pa gbogbo àwọn alufaa ibi ìrúbọ lórí pẹpẹ ìrúbọ wọn, ó sì jó egungun eniyan lórí gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ náà. Lẹ́yìn náà, ó pada sí Jerusalẹmu. +Josaya pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá fún ògo OLUWA Ọlọrun wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu ìwé majẹmu; +nítorí pé wọn kò ti ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá mọ́ láti àkókò àwọn onídàájọ́ ati ti àwọn ọba Israẹli ati Juda. +Ṣugbọn ní ọdún kejidinlogun tí Josaya ti jọba ni àwọn eniyan ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá fún ògo OLUWA ní Jerusalẹmu. +Josaya ọba lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó jáde kúrò ní Jerusalẹmu, ó sì kó àwọn ère, àwọn oriṣa, ati gbogbo ohun ìbọ̀rìṣà kúrò ní Jerusalẹmu ati ilẹ̀ Juda, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu òfin tí ó wà ninu ìwé tí Hilikaya olórí alufaa rí ninu ilé OLUWA. +Ṣáájú Josaya ati lẹ́yìn rẹ̀, kò sí ọba kankan tí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀, gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ati gbogbo agbára rẹ̀ sin Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu gbogbo òfin Mose. +Ṣugbọn sibẹsibẹ ibinu gbígbóná OLUWA tí ó ti ru sókè sí Juda nítorí ìwà burúkú Manase kò rọlẹ̀. +OLUWA sọ pé, “N óo ṣe ohun tí mo ṣe sí Israẹli sí Juda, n óo pa àwọn eniyan Juda run, n óo sì kọ Jerusalẹmu, ìlú tí mo yàn sílẹ̀, ati ilé OLUWA tí mo yàn fún ìsìn mi.” +Gbogbo nǹkan yòókù tí Josaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. +Ní àkókò tí Josaya jọba ni Neko, ọba Ijipti kó ogun rẹ̀ wá sí etí odò Yufurate láti ran ọba Asiria lọ́wọ́. Josaya pinnu láti dá ogun Ijipti pada ní Megido, ṣugbọn ó kú lójú ogun náà. +Ọba dúró sí ààyè rẹ̀, lẹ́bàá òpó, ó bá OLUWA dá majẹmu pé òun óo máa rìn ní ọ̀nà OLUWA ati láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ ati láti mú gbogbo ohun tí ó wà ninu Ìwé náà ṣẹ. Gbogbo àwọn eniyan sì ṣe ìlérí láti pa majẹmu náà mọ́. +Àwọn olórí ogun rẹ̀ gbé òkú rẹ̀ sinu kẹ̀kẹ́ ogun kan láti Megido wọn gbé e wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sinu ibojì rẹ̀.Àwọn eniyan Juda sì fi òróró yan Jehoahasi ọmọ rẹ̀ ní ọba. +Ẹni ọdún mẹtalelogun ni Jehoahasi nígbà tí ó jọba ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali, ọmọ Jeremaya, ará Libina. +Òun náà ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀. +Neko ọba Ijipti mú Jehoahasi ní ìgbèkùn ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati, kí ó má baà jọba lórí Jerusalẹmu mọ́. Ó sì mú kí Juda san ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka ati ìwọ̀n talẹnti wúrà kan bí ìṣákọ́lẹ̀. +Neko sì fi Eliakimu, ọmọ Josaya, jọba dípò rẹ̀, ṣugbọn ó yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jehoiakimu. Neko mú Jehoahasi lọ sí Ijipti, ibẹ̀ ni ó sì kú sí. +Jehoiakimu ọba gba owó orí lọ́wọ́ àwọn eniyan gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ wọn ti pọ̀ tó, láti rí owó san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Ijipti gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún un. +Jehoiakimu jẹ́ ẹni ọdún mẹẹdọgbọn nígbà tí ó jọba, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sebida, ọmọ Pedaaya, láti ìlú Ruma. +Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀. +Josaya bá pàṣẹ fún Hilikaya olórí alufaa, ati àwọn alufaa yòókù ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, pé kí wọ́n kó gbogbo ohun èlò ìsìn oriṣa Baali, ati ti oriṣa Aṣera, ati ti àwọn ìràwọ̀ jáde. Ọba jó àwọn ohun èlò náà níná lẹ́yìn odi ìlú, lẹ́bàá àfonífojì Kidironi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó eérú wọn lọ sí Bẹtẹli. +Gbogbo àwọn alufaa tí àwọn ọba Juda ti yàn láti máa rúbọ lórí pẹpẹ oriṣa ní àwọn ìlú Juda ati ní agbègbè Jerusalẹmu ni Josaya dá dúró, ati gbogbo àwọn tí wọn ń rúbọ sí oriṣa Baali, sí oòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, ati àwọn nǹkan tí wọ́n wà ní òfuurufú. +Ó kó gbogbo àwọn ère oriṣa Aṣera tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí àfonífojì Kidironi lẹ́yìn Jerusalẹmu. Ó sun wọ́n níná níbẹ̀, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì fọ́n eérú wọn ká sórí ibojì àwọn eniyan. +Ó wó gbogbo ibi tí àwọn tí wọ́n máa ń ṣe panṣaga fún ìsìn Aṣera ń gbé létí ilé OLUWA lulẹ̀, níbi tí àwọn obinrin ti máa ń hun aṣọ fún ìsìn Aṣera. +Gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà káàkiri ilẹ̀ Juda ni ó mú wá sí Jerusalẹmu, ó sì ba gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí wọ́n ti ń rúbọ jẹ́. Ó wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní ẹnubodè, tí Joṣua, baálẹ̀ ìlú kọ́, tí ó wà ní apá òsì, bí eniyan bá ti fẹ́ wọ ìlú. +Kò gba àwọn alufaa náà láàyè láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA, ṣugbọn wọ́n lè jẹ ninu àkàrà tí wọn kò fi ìwúkàrà ṣe, tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ wọn. +Josaya pa Ìbọ̀rìṣà Run. +Ní àkókò ìjọba Jehoiakimu ni Nebukadinesari, ọba Babiloni gbógun ti Jerusalẹmu, Jehoiakimu sì di iranṣẹ rẹ̀ fún ọdún mẹta. Lẹ́yìn náà, ó pada lẹ́yìn Nebukadinesari, ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí i. +Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ ogun Nebukadinesari, ọba Babiloni, lọ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dó tì í. +Ní àkókò tí wọ́n dó ti ìlú náà ni Nebukadinesari ọba Babiloni lọ sibẹ. +Ní ọdún kẹjọ tí ọba Babiloni jọba ni Jehoiakini ọba Juda jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba Babiloni, ó sì jọ̀wọ́ ìyá rẹ̀, àwọn iranṣẹ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ pẹlu, ọba Babiloni bá kó wọn ní ìgbèkùn. +Ó kó gbogbo àwọn ìṣúra ilé OLUWA ati àwọn ìṣúra tí ó wà ní ààfin. Gbogbo ohun èèlò wúrà tí wọ́n wà ninu ilé OLUWA, tí Solomoni ọba Israẹli ṣe, ni ó gé sí wẹ́wẹ́, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ tẹ́lẹ̀. +Ó kó gbogbo Jerusalẹmu ní ìgbèkùn; gbogbo àwọn ìjòyè, àwọn akọni, àwọn oníṣẹ́ ọwọ́, ati àwọn alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaarun (10,000), kò ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan ní ìlú náà, àfi àwọn talaka. +Ó kó ọba Jehoiakini, ati ìyá rẹ̀, ati àwọn aya rẹ̀, àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni. +Ọba Babiloni kó ẹẹdẹgbaarin (7,000) àwọn akọni ní ìgbèkùn ati ẹgbẹrun kan (1,000) àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ati alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ alágbára tí wọ́n lè jagun. +Ó fi Matanaya, arakunrin Jehoiakini jọba dípò rẹ̀, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Sedekaya. +Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó wà lórí oyè, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina. +Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jehoiakimu baba rẹ̀. +OLUWA bá rán àwọn ọmọ ogun Kalidea, ati ti Siria, ti Moabu, ati ti Amoni, láti pa Juda run bí ọ̀rọ̀ ti OLUWA sọ láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. +Nítorí náà, OLUWA bínú sí Jerusalẹmu ati Juda; ó sì lé wọn kúrò níwájú rẹ̀.Sedekaya sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni. +Ìjìyà yìí dé bá Juda láti ọ̀dọ̀ OLUWA, láti pa wọ́n run kúrò níwájú rẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Manase ọba, +ati nítorí ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀, nítorí tí ó ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní gbogbo ìgboro Jerusalẹmu, OLUWA kò ní dáríjì í. +Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoiakimu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. +Jehoiakimu kú, Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ọba Ijipti kò lè jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ mọ́, nítorí pé ọba Babiloni ti gba gbogbo ilẹ̀ ọba Ijipti láti odò Ijipti títí dé odò Yufurate. +Ẹni ọdún mejidinlogun ni Jehoiakini nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Nehuṣita, ọmọ Elinatani ará Jerusalẹmu. +Òun náà ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi baba rẹ̀. +Jehoiakini, Ọba Juda. +Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa ọdún kẹsan-an ìjọba rẹ̀, Nebukadinesari, ọba Babiloni, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ odi yí i ká. +Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea, tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata. +Nebusaradani kó àwọn tí wọ́n kù láàrin ìlú ati àwọn tí wọ́n sá tọ ọba Babiloni lọ, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn yòókù lọ sí ìgbèkùn. +Ṣugbọn ó fi díẹ̀ ninu àwọn talaka sílẹ̀ láti máa tọ́jú ọgbà àjàrà ati láti máa dáko. +Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada bàbà ńlá tí ó wà ninu ilé OLUWA pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, wọ́n fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó gbogbo bàbà wọn lọ sí Babiloni. +Wọ́n kó àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀kọ̀, àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń pa iná lẹ́nu àtùpà, àwọn àwo turari ati àwọn ohun èlò bàbà tí wọ́n máa ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA. +Bákan náà, wọ́n kó àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwo kòtò, gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti wúrà ati fadaka, ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ. +Bàbà tí Solomoni fi ṣe àwọn òpó mejeeji, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kọjá wíwọ̀n. +Gíga ọ̀kan ninu àwọn òpó náà jẹ́ igbọnwọ mejidinlogun, ọpọ́n idẹ tí ó wà lórí rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta, wọ́n fi bàbà ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati pomegiranate yí ọpọ́n náà ká, òpó keji sì dàbí ti àkọ́kọ́ pẹlu ẹ̀wọ̀n bàbà náà. +Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraya olórí alufaa, ati Sefanaya igbákejì alufaa, ati àwọn aṣọ́nà mẹta. +Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun ní ìlú ati àwọn aṣojú ọba marun-un tí ó rí ninu ìlú ati akọ̀wé olórí ogun, tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan ilẹ̀ náà sílẹ̀ fún ogun jíjà, ati ọgọta ọkunrin tí ó rí ninu ìlú náà. +Wọ́n dó ti ìlú náà títí di ọdún kọkanla ìjọba Sedekaya. +Nebusaradani kó gbogbo wọn lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila. +Ọba Babiloni lù wọ́n, ó sì pa wọ́n sórí ilẹ̀ Hamati.Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe kó Juda ní ìgbèkùn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀. +Nebukadinesari ọba Babiloni yan Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani ní gomina lórí àwọn tí wọ́n kù ní ilẹ̀ Juda. +Nígbà tí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu ṣe Gomina ní ilẹ̀ Juda, àwọn pẹlu àwọn eniyan wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n wá ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraya, ọmọ Tanhumeti, ará Netofa, ati Jaasanaya, ọmọ ará Maakati. +Gedalaya bá búra fún wọn, ó ní: “Ẹ má ṣe bẹ̀rù nítorí àwọn olórí Kalidea, ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa sin ọba Babiloni, yóo sì dára fun yín.” +Ṣugbọn ní oṣù keje Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, ọmọ Eliṣama, láti ìdílé ọba, pẹlu àwọn ọkunrin mẹ́wàá dojú kọ Gedalaya, wọ́n sì pa òun, ati àwọn Juu ati àwọn ará Kalidea tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Misipa. +Ni gbogbo wọn, àtọmọdé, àtàgbà, ati àwọn olórí ogun bá gbéra, wọ́n kó lọ sí Ijipti, nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kalidea bà wọ́n. +Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí wọ́n ti mú Jehoiakini ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù kejila ọdún náà, Efilimerodaki, ọba Babiloni, gbé ọ̀rọ̀ Jehoiakini yẹ̀wò, ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀ kúrò ní ẹ̀wọ̀n. +Ó bá a sọ̀rọ̀ rere, ó sì fi sí ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Babiloni lọ. +Jehoiakini bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n kúrò lọ́rùn, ó sì ń bá ọba jẹun lórí tabili ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. +Ní ọjọ́ kẹsan-an oṣù kẹrin, ìyàn náà mú láàrin ìlú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan kò fi rí oúnjẹ jẹ mọ́. +Ọba Babiloni rí i pé òun ń pèsè ohun tí ó nílò ní ojoojumọ fún un, títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. +Nígbà náà ni wọ́n lu odi ìlú náà, ọba ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n lu odi ìlú náà, wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin odi mejeeji lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, wọ́n sì gba ọ̀nà tí ó lọ sí Araba. +Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa Sedekaya, wọ́n bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì túká kúrò lẹ́yìn rẹ̀. +Ọwọ́ wọn tẹ Sedekaya, wọ́n bá mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ó sì dá ẹjọ́ fún un. +Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni Nebukadinesari ọba yọ ojú Sedekaya, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì mú un lọ sí Babiloni. +Ní ọjọ́ keje oṣù karun-un ọdún kọkandinlogun ìjọba Nebukadinesari, ọba Babiloni, Nebusaradani, tí ń ṣiṣẹ́ fún ọba Babiloni, tí ó sì tún jẹ́ olórí àwọn tí ń ṣọ́ Babiloni wá sí Jerusalẹmu. +Ó sun ilé OLUWA níná, ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn ilé ńláńlá tí ó wà níbẹ̀ ni ó sì dáná sun. +Ìṣubú Jerusalẹmu. +Ní ọdún kejidinlogun tí Jehoṣafati jọba ní Juda, Joramu, ọmọ Ahabu, jọba lórí Israẹli ní Samaria. Ó sì wà lórí oyè fún ọdún mejila. +Joramu ọba ní, “Ó mà ṣe o, OLUWA pe àwa ọba mẹtẹẹta jọ láti fi wá lé ọba Moabu lọ́wọ́.” +Ó bá bèèrè pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA kan níhìn-ín tí ó lè bá wa wádìí lọ́wọ́ OLUWA?”Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Joramu bá dáhùn pé, “Eliṣa ọmọ Ṣafati, tí ó jẹ́ iranṣẹ Elija, wà níhìn-ín.” +Jehoṣafati dáhùn pé, “Wolii òtítọ́ ni.” Àwọn ọba mẹtẹẹta náà bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. +Eliṣa sọ fún Joramu ọba pé, “Lọ sọ́dọ̀ àwọn wolii baba ati ìyá rẹ. Àbí, kí ló pa èmi ati ìwọ pọ̀?”Joramu dáhùn pé, “Rárá, OLUWA ni ó ti pe àwa ọba mẹtẹẹta yìí jọ láti fi wá lé ọba Moabu lọ́wọ́.” +Eliṣa bá dáhùn pé, “Bí OLUWA àwọn ọmọ ogun, ẹni tí mò ń sìn ṣe wà láàyè, n kì bá tí dá ọ lóhùn bí kò bá sí ti Jehoṣafati, ọba Juda, tí ó bá ọ wá.” +Ó ní, “Ẹ pe akọrin kan wá.”Bí akọrin náà ti ń kọrin ni agbára OLUWA bà lé Eliṣa, +ó bá ní, “OLUWA ní òun óo sọ àwọn odò gbígbẹ wọnyi di adágún omi. +Ẹ kò ní rí ìjì tabi òjò, sibẹsibẹ àwọn odò gbígbẹ náà yóo kún fún omi, ti yóo fi jẹ́ pé ẹ̀yin ati àwọn mààlúù yín ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóo rí ọpọlọpọ omi mu. +Nǹkan kékeré ni èyí jẹ́ níwájú OLUWA, yóo fun yín ní agbára láti borí àwọn ará Moabu. +Ẹ óo ṣẹgun àwọn ìlú olódi ati àwọn ìlú dáradára wọn, ẹ óo gé gbogbo igi dáradára, ẹ ó dí gbogbo orísun omi wọn; ẹ óo sì da òkúta sí gbogbo ilẹ̀ oko wọn.” +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA, ṣugbọn ó wó òpó oriṣa Baali tí Baba rẹ̀ mọ, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì pọ̀ tó ti baba rẹ̀ tabi ti Jesebẹli ìyá rẹ̀. +Ní ọjọ́ keji, ní àkókò ìrúbọ òwúrọ̀, omi ya wá láti apá Edomu, títí tí gbogbo ilẹ̀ fi kún fún omi. +Nígbà tí àwọn ará Moabu gbọ́ pé àwọn ọba mẹtẹẹta ń bọ̀ láti gbógun tì wọ́n, wọ́n pe gbogbo àwọn tí wọ́n lè lọ sógun jọ, ati àgbà ati ọmọde, wọ́n sì fi wọ́n sí àwọn ààlà ilẹ̀ wọn. +Nígbà tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, tí oòrùn ń ràn sórí omi náà, àwọn ará Moabu rí i pé omi tí ó wà níwájú àwọn pọ́n bí ẹ̀jẹ̀. +Wọ́n kígbe pé, “Ẹ wo ẹ̀jẹ̀! Dájúdájú àwọn ọba mẹtẹẹta wọnyi ti bá ara wọn jà, wọ́n sì ti pa ara wọn, ẹ jẹ́ kí á lọ kó ìkógun ninu ibùdó-ogun wọn.” +Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé ibùdó-ogun náà, àwọn ọmọ ogun Israẹli kọlù wọ́n, títí tí wọ́n fi sá pada; wọ́n sì ń pa wọ́n ní ìpakúpa bí wọ́n ti ń lé wọn lọ. +Wọ́n pa àwọn ìlú wọn run, gbogbo ilẹ̀ oko tí ó dára ni wọ́n da òkúta sí títí tí gbogbo wọn fi kún. Wọ́n dí gbogbo orísun omi, wọ́n sì gé gbogbo àwọn igi dáradára. Kiri Heresi tíí ṣe olú-ìlú wọn nìkan ni wọn kò pa run, ṣugbọn àwọn tí wọn ń ta kànnàkànnà yí i ká, wọ́n sì ṣẹgun rẹ̀. +Nígbà tí ọba Moabu rí i pé ogun náà le pupọ, ó mú ẹẹdẹgbẹrin (700) ọkunrin tí wọ́n ń lo idà, ó gbìyànjú láti la ààrin ogun kọjá níwájú ọba Edomu, ṣugbọn kò ṣeéṣe. +Nítorí náà, ó fi àkọ́bí rẹ̀ ọkunrin, tí ó yẹ kí ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ rú ẹbọ sísun sí oriṣa Moabu, ní orí odi ìlú náà. Ibinu ńlá dé bá àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fi í sílẹ̀, wọ́n pada lọ sí ilẹ̀ wọn. +Ó mú kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀ lọpọlọpọ gẹ́gẹ́ bíi Jeroboamu, tí ó ti jọba ṣáájú kò sì ronupiwada. +Meṣa, ọba Moabu, a máa sin aguntan; ní ọdọọdún, a máa fún ọba Israẹli ní ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọ̀dọ́ aguntan ati irun ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) àgbò, gẹ́gẹ́ bí ìṣákọ́lẹ̀. +Ṣugbọn lẹ́yìn tí Ahabu kú, ọba Moabu ṣọ̀tẹ̀, kò san ìṣákọ́lẹ̀ náà fún ọba Israẹli mọ́. +Joramu ọba bá gbéra ní Samaria, ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ. +Ó ranṣẹ sí Jehoṣafati ọba Juda pé, “Ọba Moabu ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ṣé o óo bá mi lọ láti bá a jagun?”Jehoṣafati dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, n óo lọ, ìwọ ni o ni mí, ìwọ ni o sì ni àwọn ọmọ ogun mi ati àwọn ẹṣin mi pẹlu.” +Jehoṣafati bèèrè pé, “Ọ̀nà wo ni a óo gbà lọ?”Joramu sì dáhùn pé, “Ọ̀nà aṣálẹ̀ Edomu ni.” +Ni Joramu, ati ọba Juda ati ọba Edomu bá gbéra láti lọ sójú ogun. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn fún ọjọ́ meje, kò sí omi mímu mọ́ fún wọn ati fún àwọn ẹranko tí wọ́n ru ẹrù wọn. +Ogun láàrin Israẹli ati Moabu. +Iyawo ọ̀kan ninu àwọn ọmọ àwọn wolii tọ Eliṣa lọ, ó sì sọ fún un pé, “Olúwa mi, iranṣẹ rẹ, ọkọ mi, ti kú, gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ó jẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA nígbà ayé rẹ̀. Ẹnìkan tí ó jẹ lówó kí ó tó kú fẹ́ kó àwọn ọmọkunrin mi mejeeji lẹ́rú, nítorí gbèsè baba wọn.” +Jẹ́ kí á ṣe yàrá kékeré kan sí òkè ilé wa, kí á gbé ibùsùn, tabili, àga ati fìtílà sibẹ, kí ó lè máa dé sibẹ nígbàkúùgbà tí ó bá wá síbí.” +Ní ọjọ́ kan tí Eliṣa pada lọ sí Ṣunemu, ó wọ inú yàrá náà lọ láti sinmi. +Ó bá rán Gehasi iranṣẹ rẹ̀ kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó wọlé ó dúró níwájú Eliṣa. +Eliṣa sọ fún Gehasi kí ó bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà ohun tí ó fẹ́ kí òun ṣe fún un, fún gbogbo nǹkan tí ó ti ṣe fún àwọn. Ó ní, bóyá ó fẹ́ kí òun sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba ni tabi fún balogun? Obinrin náà dáhùn pé ààrin àwọn eniyan òun ni òun ń gbé. +Eliṣa bá bèèrè lọ́wọ́ Gehasi pé, “Kí ni mo lè ṣe fún un nígbà náà?”Gehasi ní, “Kò bímọ, ọkọ rẹ̀ sì ti di arúgbó.” +Eliṣa bá rán Gehasi kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó dé, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà. +Eliṣa sọ fún un pé, “Níwòyí àmọ́dún, o óo fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọkunrin.” Obinrin náà dáhùn pé, “Háà! Oluwa mi, eniyan Ọlọrun ni ọ́, nítorí náà má ṣe parọ́ fún iranṣẹbinrin rẹ.” +Ṣugbọn obinrin náà lóyún ó sì bí ọmọkunrin ní akoko náà ní ọdún tí ó tẹ̀lé e gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Eliṣa. +Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí ọmọ náà dàgbà, ó lọ bá baba rẹ̀ ninu oko níbi tí wọ́n ti ń kórè. +Lójijì, ó kígbe pe baba rẹ̀, ó ní, “Orí mi! Orí mi!”Baba rẹ̀ sì sọ fún iranṣẹ kan kí ó gbé ọmọ náà lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀. +Eliṣa bèèrè pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ? Sọ ohun tí o ní nílé fún mi.”Obinrin náà dáhùn pé, “N kò ní ohunkohun, àfi ìkòkò òróró kan.” +Nígbà tí iranṣẹ náà gbé ọmọ náà dé ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ gbé e lé ẹsẹ̀ títí ọmọ náà fi kú ní ọ̀sán ọjọ́ náà. +Obinrin náà bá gbé òkú ọmọ náà lọ sí yàrá Eliṣa, ó tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn rẹ̀, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì jáde. +Ó kígbe pe ọkọ rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ rán iranṣẹ kan sí mi pẹlu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan. Mo fẹ́ sáré lọ rí eniyan Ọlọ́run, n óo pada dé kíákíá.” +Ọkọ rẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ rí i lónìí? Òní kì í ṣe ọjọ́ oṣù tuntun tabi ọjọ́ ìsinmi.”Ó sì dáhùn pé, “Kò séwu.” +Lẹ́yìn tí wọ́n ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ní gàárì tán, ó sọ fún iranṣẹ náà pé, “Jẹ́ kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà máa sáré dáradára, kí ó má sì dẹ̀rìn, àfi bí mo bá sọ pé kí ó má sáré mọ́.” +Ó lọ bá Eliṣa ní orí òkè Kamẹli.Eliṣa rí i tí ó ń bọ̀ lókèèrè, ó bá sọ fún Gehasi, iranṣẹ rẹ̀, pé, “Wò ó! Obinrin ará Ṣunemu nì ni ó ń bọ̀ yìí! +Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì bèèrè alaafia rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀ ati ti ọmọ rẹ̀ pẹlu.”Obinrin náà dá Gehasi lóhùn pé, “Alaafia ni gbogbo wa wà.” +Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú. Gehasi súnmọ́ ọn láti tì í kúrò, ṣugbọn Eliṣa wí fún un pé, “Fi obinrin náà sílẹ̀, ṣé o kò rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi ni? OLUWA kò sì bá mi sọ nǹkankan nípa rẹ̀.” +Obinrin náà bá sọ fún Eliṣa pé, “Ǹjẹ́ mo tọrọ ọmọ lọ́wọ́ rẹ bí? Ǹjẹ́ n kò sọ fún ọ kí o má ṣe tàn mí jẹ?” +Eliṣa bá sọ fún Gehasi pé, “Ṣe gírí, kí o mú ọ̀pá mi lọ́wọ́, kí o sì máa lọ. Bí o bá pàdé ẹnikẹ́ni lọ́nà, má ṣe kí i, bí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má dáhùn.” +Eliṣa sọ fún un pé, “Lọ yá ọpọlọpọ ìkòkò lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò rẹ. +Nígbà náà ni ìyá ọmọ náà wí pé “Bí OLUWA tí ń bẹ láàyè tí ẹ̀mí ìwọ pàápàá sì ń bẹ, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Gehasi bá dìde, ó bá a lọ. +Ó lọ fi ọ̀pá Eliṣa lé ọmọ náà lójú, ṣugbọn ọmọ náà kò jí. Ó bá pada lọ sọ fún Eliṣa pé ọmọ náà kò jí. +Nígbà tí Eliṣa dé ilé náà, ó bá òkú ọmọ náà lórí ibùsùn. +Ó wọlé síbi tí òkú ọmọ náà wà, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì gbadura sí OLUWA. +Ó nà gbalaja lé ọmọ náà lórí, ó fẹnu kò ó lẹ́nu, ó fojú kò ó lójú, ó sì gbé ọwọ́ lé ọwọ́ rẹ̀. Bí ó sì ti nà lé ọmọ náà, ara ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ wọ́ọ́rọ́. +Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó rìn síwá sẹ́yìn ninu ilé náà, ó tún pada lọ nà lé ọmọ náà. Ọmọ náà sín lẹẹmeje, ó sì la ojú rẹ̀. +Lẹ́yìn náà, ó wí fún Gehasi pé kí ó pe obinrin ará Ṣunemu náà wá, Gehasi bá pè é. Nígbà tí obinrin náà dé, Eliṣa wí fún un pé kí ó gba ọmọ rẹ̀. +Obinrin náà wólẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú ọmọ rẹ̀, ó sì jáde lọ. +Eliṣa dé sí Giligali nígbà tí ìyàn wà ní ilẹ̀ náà. Bí àwọn ọmọ wolii ti jókòó níwájú rẹ̀, ó sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbé ìkòkò ńlá léná kí ẹ sì se àsáró fún àwọn ọmọ wolii.” +Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ náà lọ sí oko láti já ewébẹ̀, ó rí àjàrà tí ó máa ń hù ninu igbó, ó sì ká ninu èso rẹ̀. Nígbà tí ó dé ilé, ó rẹ́ wọn sinu ìkòkò àsáró náà láìmọ̀ ohun tí wọ́n jẹ́. +Lẹ́yìn náà, kí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ wọlé, nígbà tí ẹ bá sì ti ti ìlẹ̀kùn yín tán, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí da òróró náà sinu àwọn ìkòkò náà, kí ẹ sì máa gbé wọn sí ẹ̀gbẹ́ kan bí wọ́n bá ti ń kún.” +Wọ́n bu oúnjẹ fún àwọn ọmọ wolii láti jẹ. Bí wọ́n ti ń jẹ àsáró náà, wọ́n kígbe pé “Eniyan Ọlọrun, májèlé wà ninu ìkòkò yìí!” Wọn kò sì lè jẹ ẹ́ mọ́. +Eliṣa dáhùn, ó ní, “Ẹ bu oúnjẹ díẹ̀ wá.” Ó da oúnjẹ náà sinu ìkòkò, ó sì wí pé, “Bu oúnjẹ fún àwọn ọkunrin náà, kí wọ́n lè jẹun.” Kò sì sí oró májèlé ninu oúnjẹ náà mọ́. +Ọkunrin kan wá láti Baaliṣaliṣa, ó mú burẹdi àkọ́so èso wá fún eniyan Ọlọrun, ati ogún burẹdi tí a fi ọkà-baali ṣe ati ṣiiri ọkà tuntun ninu àpò rẹ̀. Eliṣa bá wí pé, “Ẹ kó wọn fún àwọn ọmọkunrin, kí wọ́n jẹ ẹ́.” +Ṣugbọn iranṣẹ rẹ̀ wí pé, “Báwo ni n óo ṣe wá gbé èyí kalẹ̀ níwájú ọgọrun-un eniyan láti jẹ?”Eliṣa tún ní, “Kó wọn fún àwọn ọmọkunrin kí wọ́n jẹ ẹ́, nítorí pé OLUWA ní, ‘Wọn yóo jẹ, yóo sì ṣẹ́kù.’ ” +Iranṣẹ náà bá gbé oúnjẹ náà kalẹ̀ níwájú àwọn ọmọkunrin náà, wọ́n jẹ, ó sì ṣẹ́kù gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA. +Obinrin náà lọ sinu ilé rẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn wọn; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí da òróró náà sinu àwọn ìkòkò náà bí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ń gbé wọn wá. +Nígbà tí gbogbo àwọn ìkòkò náà kún, obinrin náà bèèrè bóyá ìkòkò kù, àwọn ọmọ rẹ̀ sì dáhùn pé ó ti tán, òróró náà sì dá. +Ó bá pada lọ sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wolii Eliṣa. Eliṣa wí fún un pé, “Lọ ta àwọn òróró náà kí o sì san gbèsè rẹ ninu rẹ̀, kí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ máa ná ìyókù.” +Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu, níbi tí obinrin ọlọ́rọ̀ kan ń gbé; obinrin náà sì pe Eliṣa wọlé kí ó wá jẹun. Láti ìgbà náà, ilé obinrin yìí ni Eliṣa ti máa ń jẹun ní Ṣunemu. +Obinrin náà sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Mo wòye pé ọkunrin tí ó ń wá síbí yìí jẹ́ ẹni mímọ́ Ọlọ́run. +Eliṣa Ran Opó Aláìní Kan Lọ́wọ́. +Naamani, olórí ogun Siria, jẹ́ eniyan pataki ati ọlọ́lá níwájú ọba Siria, nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni OLUWA ṣe fún ilẹ̀ Siria ní ìṣẹ́gun. Ó jẹ́ akọni jagunjagun, ṣugbọn adẹ́tẹ̀ ni. +Eliṣa rán iranṣẹ kan kí ó sọ fún un pé kí ó lọ wẹ ara rẹ̀ ninu odò Jọdani ní ìgbà meje, yóo sì rí ìwòsàn. +Ṣugbọn Naamani fi ibinu kúrò níbẹ̀, ó ní, “Mo rò pé yóo jáde wá, yóo gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, yóo fi ọwọ́ rẹ̀ pa ibẹ̀, yóo sì ṣe àwòtán ẹ̀tẹ̀ náà ni. +Ṣé àwọn odò Abana ati odò Faripari tí wọ́n wà ní Damasku kò dára ju gbogbo àwọn odò tí wọ́n wà ní Israẹli lọ ni? Ṣebí mo lè wẹ̀ ninu wọn kí n sì mọ́!” Ó bá yipada, ó ń bínú lọ. +Àwọn iranṣẹ rẹ̀ bá gbà á níyànjú pé, “Baba, ṣé bí wolii náà bá sọ pé kí o ṣe ohun tí ó le ju èyí lọ, ṣé o kò ní ṣe é? Kí ló dé tí o kò lè wẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, kí o sì rí ìwòsàn gbà?” +Naamani bá lọ sí odò Jọdani, ó wẹ̀ ní ìgbà meje gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti pàṣẹ fún un, ó rí ìwòsàn, ara rẹ̀ sì jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde. +Lẹ́yìn náà ó pada pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ sọ́dọ̀ Eliṣa, ó ní, “Nisinsinyii ni mo mọ̀ pé kò sí ọlọrun mìíràn ní gbogbo ayé àfi Ọlọrun Israẹli. Nítorí náà jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn yìí lọ́wọ́ iranṣẹ rẹ.” +Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Mo fi OLUWA tí mò ń sìn búra pé n kò ní gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ.”Naamani rọ̀ ọ́ kí ó gbà wọ́n, ṣugbọn ó kọ̀. +Naamani bá ní, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ààyè láti bu erùpẹ̀ ẹrù kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ meji lọ sílé nítorí láti òní lọ, iranṣẹ rẹ kì yóo rúbọ sí ọlọrun mìíràn bíkòṣe OLUWA. +Mo bẹ̀bẹ̀ kí OLUWA dáríjì mí nígbà tí mo bá tẹ̀lé oluwa mi lọ sinu tẹmpili Rimoni, oriṣa Siria láti rúbọ sí i. Bí oluwa mi bá gbé ara lé apá mi, tí èmi náà sì tẹríba ninu tẹmpili Rimoni, kí OLUWA dáríjì iranṣẹ rẹ.” +Eliṣa sọ fún un pé “Máa lọ ní alaafia.” Naamani bá lọ.Ṣugbọn kò tíì rìn jìnnà, +Iyawo Naamani ní iranṣẹbinrin kékeré kan tí àwọn ará Siria mú lẹ́rú wá láti ilẹ̀ Israẹli, nígbà tí wọ́n lọ bá wọn jagun. +nígbà tí Gehasi, iranṣẹ Eliṣa, sọ ninu ara rẹ̀ pé, “Olúwa mi jẹ́ kí Naamani ará Siria yìí lọ láì gba ohun tí ó mú wá lọ́wọ́ rẹ̀. Mo fi OLUWA búra pé, n óo sáré tẹ̀lé e láti gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀.” +Ó bá sáré tẹ̀lé Naamani. Nígbà tí Naamani rí i pé ẹnìkan ń sáré bọ̀, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ogun tí ó gùn láti pàdé rẹ̀, ó bèèrè pé, “Ṣé kò sí nǹkan?” +Gehasi dáhùn pé, “Rárá, kò sí nǹkan. Oluwa mi ni ó rán mi sí ọ pé, ‘Nisinsinyii ni meji ninu àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọn ń gbé òkè Efuraimu wá sọ́dọ̀ mi. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ìwọ̀n talẹnti fadaka kan ati aṣọ meji.’ ” +Naamani sì rọ̀ ọ́ kí ó gba ìwọ̀n talẹnti meji. Ó di owó náà sinu àpò meji pẹlu aṣọ meji. Ó pàṣẹ fún iranṣẹ meji kí wọ́n bá Gehasi gbé wọn lọ. +Nígbà tí wọ́n dé orí òkè tí Eliṣa ń gbé, Gehasi gba àwọn ẹrù náà lórí wọn, ó gbé wọn sinu ilé, ó sì dá àwọn iranṣẹ Naamani pada. +Nígbà tí ó wọlé, Eliṣa bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni o lọ?”Ó dáhùn pé, “N kò lọ sí ibìkan kan.” +Eliṣa dáhùn pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé mo wà pẹlu rẹ ninu ẹ̀mí, nígbà tí Naamani sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́-ogun, tí ó gùn, tí ó wá láti pàdé rẹ? Ṣé àkókò yìí ni ó yẹ láti gba fadaka tabi aṣọ tabi olifi tabi ọgbà àjàrà tabi aguntan tabi mààlúù tabi iranṣẹkunrin tabi iranṣẹbinrin? +Nítorí ìdí èyí, ẹ̀tẹ̀ Naamani yóo lẹ̀ mọ́ ọ lára ati ìdílé rẹ ati ìrandíran rẹ títí lae.”Gehasi sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Eliṣa ní adẹ́tẹ̀, ó funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú. +Ní ọjọ́ kan, ọmọbinrin náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, “Bí oluwa mi Naamani bá lọ sí ọ̀dọ̀ wolii tí ó wà ní Samaria, yóo rí ìwòsàn gbà.” +Nígbà tí Naamani gbọ́, ó sọ ohun tí ọmọbinrin náà sọ fún ọba. +Ọba Siria dáhùn pé, “Tètè lọ, n óo sì fi ìwé ranṣẹ sí ọba Israẹli.”Naamani mú ìwọ̀n talẹnti fadaka mẹ́wàá ati ẹgbaata (6,000) ìwọ̀n ṣekeli wúrà ati ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá, +ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Israẹli pẹlu ìwé náà. Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé náà nìyí, “Ẹni tí ó mú ìwé yìí wá ni Naamani, iranṣẹ mi, mo rán an wá sọ́dọ̀ rẹ kí o lè wò ó sàn ninu àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.” +Nígbà tí ọba Israẹli ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbẹ̀rù rẹ̀ hàn, ó sì wí pé, “Èmi ha í ṣe Ọlọrun tí ó ní agbára ikú ati ìyè bí, tí ọba Siria fi rò wí pé mo lè wo eniyan sàn kúrò ninu ẹ̀tẹ̀? Èyí fi hàn pé ó ń wá ìjà ni.” +Nígbà tí Eliṣa gbọ́ pé ọba Israẹli ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ranṣẹ sí i pé, “Kí ló dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Mú ọkunrin náà wá sọ́dọ̀ mi, kí ó lè mọ̀ pé wolii kan wà ní Israẹli.” +Naamani bá lọ ti òun ti àwọn ẹṣin ati kẹ̀kẹ́-ogun rẹ̀, ó sì dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé Eliṣa. +Naamani Gba Ìwòsàn. +Ní ọjọ́ kan àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọ́n wà lábẹ́ àkóso Eliṣa sọ fún un pé, “Ibi tí à ń gbé kéré jù fún wa. +Ọba Israẹli bá ranṣẹ sí àwọn eniyan tí ń gbé ibi tí Eliṣa kilọ̀ fún un nípa rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ níí máa ń kìlọ̀ fún ọba Israẹli tí ọba Israẹli sì ń bọ́ kúrò ninu tàkúté ọba Siria. Ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ọpọlọpọ ìgbà. +Ọkàn ọba Siria kò balẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ yìí, nítorí náà, ó pe gbogbo àwọn olórí ogun rẹ̀ jọ, ó sì bi wọ́n pé, “Ta ló ń tú àṣírí wa fún ọba Israẹli ninu yín?” +Ọ̀kan ninu wọn dáhùn pé, “Kò sí ẹnìkan ninu wa tí ń sọ àṣírí fún ọba Israẹli. Wolii Eliṣa ní ń sọ fún un, títí kan gbogbo ohun tí ẹ bá sọ ní kọ̀rọ̀ yàrá yín.” +Ọba bá pàṣẹ pé, “Ẹ lọ wádìí ibi tí ó ń gbé, kí n lè ranṣẹ lọ mú un.”Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé Eliṣa wà ní Dotani, +ó rán ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun ati ẹṣin ati kẹ̀kẹ́-ogun lọ sibẹ. Ní òru ni wọ́n dé ìlú náà, wọ́n sì yí i po. +Ní òwúrọ̀ kutukutu, nígbà tí iranṣẹ Eliṣa jáde sí ìta, ó rí i pé àwọn ọmọ ogun Siria ti yí ìlú náà po pẹlu ẹṣin ati àwọn kẹ̀kẹ́-ogun. Ó pada wọlé tọ Eliṣa lọ, ó sì kígbe pé, “Yéè, oluwa mi, kí ni a óo ṣe?” +Eliṣa dáhùn pé, “Má bẹ̀rù nítorí pé àwọn tí wọ́n wà pẹlu wa ju àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn lọ.” +Eliṣa bá gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ ṣí ojú rẹ̀, kí ó lè ríran. OLUWA ṣí iranṣẹ náà lójú, ó sì rí i pé gbogbo orí òkè náà kún fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, iná sí yí Eliṣa ká. +Nígbà tí àwọn ará Siria gbìyànjú láti mú un, ó gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ fọ́ àwọn ọkunrin náà lójú. OLUWA sì fọ́ wọn lójú gẹ́gẹ́ bí adura Eliṣa. +Eliṣa tọ̀ wọ́n lọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣìnà; èyí kì í ṣe ìlú tí ẹ̀ ń wá, ẹ tẹ̀lé mi n óo fi ẹni tí ẹ̀ ń wá hàn yín.” Ó sì mú wọn lọ sí Samaria. +Jọ̀wọ́ fún wa ní ààyè láti lọ gé igi ní etí odò Jọdani láti fi kọ́ ilé mìíràn tí a óo máa gbé.”Eliṣa dáhùn pé, “Ó dára, ẹ máa lọ.” +Ní kété tí wọ́n wọ Samaria, Eliṣa gbadura pé kí OLUWA ṣí wọn lójú kí wọ́n lè ríran. OLUWA sì ṣí wọn lójú, wọ́n rí i pé ààrin Samaria ni àwọn wà. +Nígbà tí ọba Israẹli rí wọn, ó bi Eliṣa pé, “Ṣé kí n pa wọ́n, oluwa mi, ṣé kí n pa wọ́n?” +Eliṣa dáhùn pé, “O kò gbọdọ̀ pa wọ́n, ṣé o máa pa àwọn tí o bá kó lójú ogun ni? Gbé oúnjẹ ati omi kalẹ̀ níwájú wọn, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n mu, kí wọ́n sì pada sọ́dọ̀ oluwa wọn.” +Nítorí náà, ọba Israẹli pèsè oúnjẹ fún wọn lọpọlọpọ. Lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n sì ti mu, wọ́n pada sọ́dọ̀ oluwa wọn. Láti ọjọ́ náà ni àwọn ọmọ ogun Siria kò ti gbógun ti ilẹ̀ Israẹli mọ́. +Lẹ́yìn èyí, Benhadadi, ọba Siria, kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti bá Israẹli jagun, wọ́n sì dóti ìlú Samaria. +Nítorí náà, ìyàn ńlá mú ní ìlú náà tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ọgọrin ìwọ̀n ṣekeli fadaka ati idamẹrin òṣùnwọ̀n kabu ìgbẹ́ ẹyẹlé ní ìwọ̀n ṣekeli fadaka marun-un. +Bí ọba Israẹli ti ń rìn lórí odi ìlú, obinrin kan kígbe pè é, ó ní, “Olúwa mi, ọba, ràn mí lọ́wọ́.” +Ọba dáhùn pé, “Bí OLUWA kò bá ràn ọ́ lọ́wọ́, ìrànlọ́wọ́ wo ni èmi lè ṣe? Ṣé mo ní ìyẹ̀fun tabi ọtí waini ni?” +Ó bá bèèrè pé, “Kí ni ìṣòro rẹ?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin yìí sọ fún mi pé kí n mú ọmọ mi wá kí á pa á jẹ, bí ó bá di ọjọ́ keji a óo pa ọmọ tirẹ̀ jẹ, +ni a bá pa ọmọ tèmi jẹ. Ní ọjọ́ keji, mo sọ fún un pé kí ó mú ọmọ tirẹ̀ wá kí á pa á jẹ, ṣugbọn ó fi ọmọ tirẹ̀ pamọ́.” +Ọ̀kan ninu wọn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá àwọn lọ, ó sì gbà bẹ́ẹ̀. +Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Àwọn tí wọ́n wà lẹ́bàá odi níbi tí ó ń gbà lọ sì rí i pé ó wọ aṣọ-ọ̀fọ̀ sí abẹ́ aṣọ rẹ̀. +Ó sì búra pé kí OLUWA ṣe jù bẹ́ẹ̀ sí òun bí òun kò bá gé orí Eliṣa, ọmọ Ṣafati, kí ilẹ̀ ọjọ́ náà tó ṣú. +Eliṣa jókòó ninu ilé rẹ̀ pẹlu àwọn alàgbà. Ọba rán ọkunrin kan ṣáájú láti lọ pa á, ṣugbọn Eliṣa sọ fún àwọn alàgbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ apànìyàn yìí ti rán ẹnìkan láti wá pa mí, ọba fúnra rẹ̀ sì ń tẹ̀lé e bọ̀ lẹ́yìn. Bí iranṣẹ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà kí ó má lè wọlé.” +Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dé, ó ní, “Láti ọ̀dọ̀ OLUWA ni ibi yìí ti wá, kí ló dé tí n óo fi tún máa dúró de OLUWA fún ìrànlọ́wọ́?” +Gbogbo wọn jọ lọ, nígbà tí wọ́n dé etí odò Jọdani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gé igi. +Bí ọ̀kan ninu wọn ti ń gé igi, lójijì, irin àáké tí ó ń lò yọ bọ́ sinu odò. Ó kígbe pé, “Yéè! Oluwa mi, a yá àáké yìí ni!” +Eliṣa bèèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?”Ọkunrin náà sì fi ibẹ̀ hàn án. Eliṣa gé igi kan, ó jù ú sinu omi, irin àáké náà sì léfòó lójú omi. +Eliṣa pàṣẹ fún un pé, “Mú un.” Ọkunrin náà bá mu irin àáké náà. +Ní ìgbà kan tí ọba Siria ń bá ọba Israẹli jagun, ó bá àwọn olórí ogun rẹ̀ gbèrò ibi tí wọn yóo ba sí de àwọn ọmọ ogun Israẹli. +Eliṣa ranṣẹ sí ọba Israẹli pé kí ó má ṣe gba ibẹ̀ nítorí pé àwọn ará Siria ba sibẹ. +Irin Àáké Léfòó. +Eliṣa dáhùn pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ní àkókò yìí lọ́la, ní ẹnubodè Samaria, àwọn eniyan yóo ra òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan, tabi òṣùnwọ̀n ọkà baali meji ní ìwọ̀n ṣekeli kan.” +Wọ́n bá lọ sí Samaria, wọ́n sì kígbe pe àwọn aṣọ́nà láti ẹnubodè pé, “A ti lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria, a kò rí ẹnìkan kan níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbúròó ẹnìkan kan. Àwọn ẹṣin ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn wà bí wọ́n ṣe so wọ́n mọ́lẹ̀, gbogbo àwọn àgọ́ wọn sì wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Siria ti fi wọ́n sílẹ̀.” +Àwọn aṣọ́nà bá sọ fún àwọn tí wọ́n wà ní ààfin ọba. +Ọba dìde ní òru ọjọ́ náà, ó sọ fún àwọn olórí ogun rẹ̀ pé, “Mo mọ ète àwọn ará Siria. Wọ́n mọ̀ pé ìyàn mú ninu ìlú wa, nítorí náà ni wọ́n ṣe fi ibùdó ogun wọn sílẹ̀ láti sá pamọ́ sinu igbó, pẹlu èrò pé a óo wá oúnjẹ wá. Kí wọ́n lè mú wa láàyè, kí wọ́n sì gba ìlú wa.” +Ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun náà dá ọba lóhùn pé, “Ṣebí àwọn eniyan náà yóo kú ni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n ti kú. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á rán àwọn ọkunrin kan pẹlu ẹṣin marun-un tí ó kù láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.” +Ọba sì rán ọkunrin meji pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun meji láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. +Àwọn ọkunrin náà lọ títí dé odò Jọdani. Ní gbogbo ojú ọ̀nà náà ni wọ́n ti ń rí àwọn aṣọ ati àwọn ohun ìjà tí àwọn ará Siria jù sọnù nígbà tí wọn ń sá lọ. Wọ́n sì pada wá ròyìn fún ọba. +Àwọn ará Samaria sì tú jáde láti lọ kó ìkógun ní ibùdó ogun àwọn ará Siria. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí OLUWA ti sọ, wọ́n ta òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan ní ìwọ̀n ṣekeli kan. +Ọba Israẹli fi ìtọ́jú ẹnubodè ìlú sí abẹ́ àkóso ọ̀gágun tí ó jẹ́ aṣojú rẹ̀. Àwọn eniyan sì tẹ ọ̀gágun náà pa, gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọtẹ́lẹ̀ nígbà tí ọba lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. +Nítorí nígbà tí eniyan Ọlọrun sọ fún ọba pé, “Ní ìwòyí ọ̀la, lẹ́nu bodè Samaria, àwọn eniyan yóo máa ra òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan tabi òṣùnwọ̀n ọkà baali meji ní ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan,” +ọ̀gágun náà dáhùn pé, “Ǹjẹ́ èyí lè ṣẹ, bí OLUWA tilẹ̀ rọ̀jò àwọn nǹkan wọnyi sílẹ̀ láti ojú ọ̀run wá.” Eliṣa sì dá a lóhùn pé, “O óo fi ojú rẹ rí i, ṣugbọn o kò ní jẹ ninu rẹ̀.” +Ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun tí wọ́n wà níbẹ̀, tí ó jẹ́ aṣojú ọba dá Eliṣa lóhùn, ó ní, “Bí OLUWA bá tilẹ̀ da àwọn nǹkan wọnyi sílẹ̀ láti ojú ọ̀run wá, ǹjẹ́ ohun tí o sọ yìí lè rí bẹ́ẹ̀?”Eliṣa dá a lóhùn pé, “O óo fi ojú rí i, ṣugbọn o kò ní jẹ ninu rẹ̀.” +Ó sì rí bẹ́ẹ̀ fún un, nítorí àwọn eniyan tẹ ọ̀gágun náà pa ní ẹnubodè ìlú. +Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹrin kan wà ní ẹnubodè Samaria, wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Kí ló dé tí a óo fi dúró síbí títí tí a óo fi kú? +Bí a bá lọ sinu ìlú ebi yóo pa wá kú nítorí ìyàn wà níbẹ̀, bí a bá sì dúró níbí, a óo kú bákan náà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria. Bí wọ́n bá pa wá, a jẹ́ pé ikú yá, bí wọ́n bá sì dá wa sí, a óo wà láàyè.” +Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí pofírí, wọ́n lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria, nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọn kò rí ẹnìkan kan. +OLUWA ti mú kí àwọn ọmọ ogun Siria gbọ́ ìró ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin ati ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Wọ́n wí fún ara wọn pé ọba Israẹli ti lọ bẹ àwọn ọmọ ogun Hiti ati ti Ijipti láti wá bá àwọn jà. +Nítorí náà, wọ́n sá lọ ní àṣáálẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n fi ibùdó ogun wọn ati àwọn ẹṣin wọn ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n sì sá àsálà fún ẹ̀mí wọn. +Nígbà tí àwọn adẹ́tẹ̀ mẹrin náà dé ìkangun ibùdó ogun, wọ́n wọ inú àgọ́ kan lọ. Wọ́n jẹ ohun tí wọ́n bá níbẹ̀; wọ́n sì mu. Wọ́n kó fadaka ati wúrà ati aṣọ tí wọ́n rí níbẹ̀, wọ́n lọ kó wọn pamọ́. Wọ́n pada wá, wọ́n wọ inú àgọ́ mìíràn, wọ́n tún ṣe bákan náà. +Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ohun tí à ń ṣe yìí kò dára, ọjọ́ ìròyìn ayọ̀ ni ọjọ́ òní. Bí a bá dákẹ́, tí a sì dúró di òwúrọ̀ a óo jìyà. Ẹ jẹ́ kí á lọ sọ fún àwọn ará ilé ọba.” +Ogun Siria pada Sílé. +Eliṣa sọ fún obinrin ará Ṣunemu, ẹni tí Eliṣa jí ọmọ rẹ̀ tí ó kú pé, “OLUWA yóo rán ìyàn sí ilẹ̀ yìí fún ọdún meje, nítorí náà, kí ìwọ ati ẹbí rẹ lọ máa gbé ní ilẹ̀ mìíràn.” +Eliṣa dáhùn pé, “OLUWA ti fi hàn mí pé yóo kú, ṣugbọn lọ sọ fún un pé yóo yè.” +Eliṣa tẹjú mọ́ Hasaeli títí ojú fi tì í. Eliṣa sì sọkún. +Hasaeli bèèrè pé, “Kí ló dé tí o fi ń sunkún, oluwa mi?”Eliṣa dáhùn pé, “Nítorí pé mo mọ oríṣìíríṣìí nǹkan burúkú tí o óo ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli: O óo jó ibi ààbò wọn, o óo fi idà pa àwọn ọmọkunrin wọn, o óo tú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn ká, o óo sì la inú àwọn aboyún wọn.” +Hasaeli dáhùn pé, “Ta ni mí, tí n óo fi ṣe nǹkan tí ó lágbára tóbẹ́ẹ̀?”Eliṣa dáhùn pé, “OLUWA ti fi hàn mí pé o óo jọba ní Siria.” +Ó bá pada lọ sọ́dọ̀ Benhadadi, ó sì bèèrè ohun tí Eliṣa sọ lọ́wọ́ rẹ̀.Hasaeli dáhùn pé, “O óo yè ninu àìsàn rẹ.” +Ní ọjọ́ keji Hasaeli mú aṣọ tí ó nípọn, ó rì í bọ omi, ó sì fi bo ojú Benhadadi títí ó fi kú.Hasaeli sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ní ọdún karun-un tí Joramu ọmọ Ahabu jọba ní Israẹli, ni Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jọba ní ilẹ̀ Juda. +Ẹni ọdún mejilelọgbọn ni, nígbà tí ó jọba, ó sì jọba fún ọdún mẹjọ. +Ó tẹ̀ sí ọ̀nà àwọn ọba Israẹli gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu nítorí ọmọ Ahabu, ni iyawo rẹ̀, ó ṣe ibi níwájú OLUWA. +Sibẹsibẹ OLUWA kò pa Juda run nítorí ó ti búra fún Dafidi iranṣẹ rẹ̀ pé ìran rẹ̀ yóo máa jọba ní ilẹ̀ Juda. +Obinrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Eliṣa, òun ati ẹbí rẹ̀ sì lọ ń gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ọdún meje. +Ní àkókò ìjọba Jehoramu, Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì yan ọba fún ara wọn. +Nítorí náà, Jehoramu kó gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí Sairi láti bá Edomu jagun. Níbẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun Edomu ti yí wọn ká. Ní òru, òun ati àwọn olórí ogun rẹ̀ kọlu àwọn ará Edomu tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n sì sá àsálà, ṣugbọn àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sá pada sí ilé wọn. +Láti ìgbà náà ni Edomu ti di òmìnira kúrò lọ́wọ́ Juda. Ní àkókò kan náà ni ìlú Libina ṣọ̀tẹ̀ sí Juda. +Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Jehoramu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. +Jehoramu kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Ahasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Ní ọdún kejila tí Joramu ọmọ Ahabu ti jọba ní Israẹli ni Ahasaya, ọmọ Jehoramu, jọba ní ilẹ̀ Juda. +Ẹni ọdún mejilelogun ni nígbà tí ó jọba ni Jerusalẹmu, ó sì jọba fún ọdún kan. Atalaya ni ìyá rẹ̀, ọmọ Omiri, ọba ilẹ̀ Israẹli. +Ọ̀nà ìdílé Ahabu ọba ni Ahasaya tẹ̀ sí, ó sì ṣe burúkú níwájú OLUWA, bí ìdílé Ahabu ti ṣe; nítorí pé àna ló jẹ́ fún Ahabu. +Ahasaya bá Joramu, ọba Israẹli lọ, wọ́n gbógun ti Hasaeli, ọba Siria, ní Ramoti Gileadi. Àwọn ọmọ ogun Siria ṣá ọba Joramu lọ́gbẹ́. +Ó pada sí ìlú Jesireeli, ó lọ wo ọgbẹ́ náà sàn. Ahasaya, ọba Juda, ọmọ Jehoramu, sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò ní Jesireeli. +Lẹ́yìn ọdún keje, obinrin náà pada sí Israẹli, ó sì lọ sọ́dọ̀ ọba láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó dá ilé ati ilẹ̀ òun pada. +Ó bá ọba tí ó ń bá Gehasi iranṣẹ Eliṣa sọ̀rọ̀; ọba fẹ́ mọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Eliṣa. +Bí Gehasi ti ń sọ fún ọba bí Eliṣa ṣe jí òkú dìde, ni obinrin tí Eliṣa jí òkú ọmọ rẹ̀ dìde wá sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba. Gehasi sọ fún ọba pé, “Olúwa mi, obinrin náà nìyí, ọmọkunrin rẹ̀ tí Eliṣa jí dìde náà sì nìyí.” +Ọba bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà, ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún ọba. Ọba bá pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ kí ó fún obinrin náà ní gbogbo ohun tíí ṣe tirẹ̀ pẹlu gbogbo ohun tí wọ́n ti kórè ninu oko náà, láti ìgbà tí obinrin náà ti fi ìlú sílẹ̀ títí di ìgbà tí ó pada dé. +Eliṣa lọ sí Damasku ní àkókò kan tí Benhadadi ọba Siria wà lórí àìsàn. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba pé Eliṣa wà ní Damasku, +ọba sọ fún Hasaeli, ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, kí o sì lọ bá wolii náà, kí o sọ fún un pé kí ó bá mi bèèrè lọ́wọ́ OLUWA bóyá n óo yè ninu àìsàn yìí.” +Hasaeli di ogoji ẹrù ràkúnmí tí ó kún fún oniruuru ohun rere tí ó wà ní Damasku, ó lọ bá Eliṣa. Nígbà tí Hasaeli pàdé rẹ̀, ó sọ pé, “Iranṣẹ rẹ, Benhadadi, ọba Siria, rán mi láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ bóyá òun óo yè ninu àìsàn òun.” +Obinrin Ará Ṣunemu náà Pada. +Eliṣa pe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ àwọn wolii, ó sọ fún un pé, “Ṣe kánkán, kí o lọ sí Ramoti Gileadi pẹlu ìgò òróró yìí. +Ajá ni yóo jẹ òkú Jesebẹli ní agbègbè Jesireeli, kò sí ẹni tí yóo sin òkú rẹ̀.” Lẹ́yìn tí ó ti sọ̀rọ̀ náà tán, ó ṣí ìlẹ̀kùn, ó sá lọ. +Nígbà tí Jehu pada sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀, wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé kò sí nǹkan? Kí ni ọkunrin bíi wèrè yìí ń wá lọ́dọ̀ rẹ?”Jehu dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ọkunrin náà, ati ohun tí ó sọ?” +Wọ́n dáhùn pé, “Rárá, a kò mọ̀ ọ́n, sọ fún wa.”Jehu sì dáhùn pé, “Ó sọ fún mi pé OLUWA ti fi òróró yàn mí ní ọba lórí Israẹli.” +Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ́ aṣọ wọn sílẹ̀ fún un kí ó dúró lé, wọ́n sì fun fèrè pé, “Kabiyesi, Jehu ọba!” +Jehu, ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi, dìtẹ̀ mọ́ Joramu. (Ní àkókò yìí Joramu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli ń ṣọ́ Hasaeli ọba Siria ní Ramoti Gileadi; +ṣugbọn Joramu ọba ti lọ sí Jesireeli láti tọ́jú ọgbẹ́ tí wọ́n ṣá a lójú ogun Siria.) Jehu sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Bí ẹ bá wà lẹ́yìn mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde kúrò ní ìlú láti lọ ròyìn fún wọn ní Jesireeli.” +Jehu gun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó lọ sí Jesireeli nítorí ibẹ̀ ni Joramu ọba wà, Ahasaya, ọba Juda sì wá bẹ̀ ẹ́ wò níbẹ̀. +Ọ̀kan ninu àwọn aṣọ́nà tí ó wà ninu ilé ìṣọ́ ní Jesireeli rí i tí Jehu ati àwọn ọkunrin rẹ̀ ń bọ̀. Ó sì kígbe pé, “Mo rí àwọn ọkunrin kan tí wọ́n ń gun kẹ̀kẹ́ ogun bọ̀.”Joramu dáhùn pé, “Rán ẹlẹ́ṣin kan láti bèèrè bóyá alaafia ni.” +Ẹlẹ́ṣin kan lọ pàdé rẹ̀, ó ní, “Ọba wí pé, ṣé alaafia ni?”Jehu dá a lóhùn pé, “Kí ni o ní ṣe pẹlu alaafia? Bọ́ sẹ́yìn mi.” Olùṣọ́ náà wí pé, “Oníṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn ṣugbọn kò pada wá.” +Wọ́n bá tún rán oníṣẹ́ mìíràn lọ láti bèèrè ìbéèrè kan náà lọ́wọ́ Jehu. Ó tún dáhùn pé “Kí ni o fẹ́ fi alaafia ṣe? Bọ́ sẹ́yìn mi.” +Nígbà tí o bá dé ibẹ̀, bèèrè Jehu, ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi; mú un wọ yàrá kan lọ kúrò láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. +Olùṣọ́ bá tún jíṣẹ́ fun ọba pé, “Oníṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣugbọn kò pada.” Ó tún fi kún un pé, “Wọ́n ń wa kẹ̀kẹ́ ogun wọn bíi Jehu, ọmọ Nimṣi, nítorí wọ́n ń wà á pẹlu ibinu.” +Joramu ọba pàṣẹ pé kí wọ́n gbé kẹ̀kẹ́ ogun òun wá, wọ́n sì gbé e wá fún un. Joramu ọba ati Ahasaya, ọba Juda sì jáde lọ pàdé Jehu, olukuluku ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Wọ́n pàdé rẹ̀ ninu oko Naboti ara Jesireeli. +Joramu bèèrè pé, “Ṣé alaafia ni?”Jehu dáhùn pé, “Alaafia ṣe lè wà níwọ̀n ìgbà tí ìwà àgbèrè ati àjẹ́ ìyá rẹ ṣì wà sibẹ.” +Joramu bá kígbe pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí, Ahasaya!” Ó yí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pada, ó ń sá lọ. +Jehu fi gbogbo agbára ta ọfà rẹ̀, ó bá Joramu lẹ́yìn, ó wọ inú ọkàn rẹ̀ lọ, Joramu sì kú sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. +Jehu sọ fún Bidikari, ẹni tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó ní, “Gbé òkú rẹ̀ kí o jù ú sinu oko Naboti. Ṣé o ranti pé, nígbà tí èmi pẹlu rẹ ń gun kẹ̀kẹ́ ogun lẹ́yìn Ahabu baba rẹ̀, OLUWA sọ ọ̀rọ̀ wọnyi nípa Ahabu, +pé, ‘Mo rí i bí o ti pa Naboti ati àwọn ọmọ rẹ̀ lánàá, dájúdájú n óo jẹ ọ́ níyà ninu oko kan náà.’ Nítorí náà gbé òkú rẹ̀ jù sinu oko Naboti gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA.” +Nígbà tí Ahasaya rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó sá gba ọ̀nà Beti Hagani lọ. Jehu bẹ̀rẹ̀ sí lépa rẹ̀, ó pàṣẹ fún àwọn ọkunrin rẹ̀ pé kí wọ́n ta á lọ́fà! Wọ́n sì ta á lọ́fà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ní ọ̀nà Guri lẹ́bàá Ibileamu, ó sá lọ sí Megido, níbẹ̀ ni ó sì kú sí. +Àwọn olórí ogun rẹ̀ gbé òkú rẹ̀ sinu kẹ̀kẹ́ ogun kan lọ sí Jerusalẹmu. Wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. +Ahasaya jọba ní ilẹ̀ Juda ní ọdún kọkanla tí Joramu ọmọ Ahabu ti jọba ní Israẹli. +Kí o da òróró inú ìgò yìí sí i lórí, kí o sì wí pé, OLUWA sọ pé, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.’ Kí o sì yára sá kúrò níbẹ̀.” +Nígbà tí Jehu dé Jesireeli, Jesebẹli gbọ́; ó lé tìróò, ó di irun rẹ̀, ó sì ń yọjú wo ìta láti ojú fèrèsé ní òkè. +Bí Jehu ti gba ẹnu ọ̀nà wọlé, Jesebẹli kígbe pé, “Ṣé alaafia ni, Simiri? Ìwọ tí o pa oluwa rẹ!” +Jehu bá gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ní, “Ta ló wà lẹ́yìn mi ninu yín?” Àwọn ìwẹ̀fà meji tabi mẹta sì yọjú sí i láti ojú fèrèsé. +Jehu bá ké sí wọn, ó ni, “Ẹ Jù ú sílẹ̀.” Wọ́n bá ju Jesebẹli sí ìsàlẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ta sí ara ògiri ati sí ara àwọn ẹṣin, àwọn ẹṣin Jehu sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ kọjá. +Lẹ́yìn náà, ó wọlé, ó jẹ, ó mu, lẹ́yìn náà, ó ní, “Ẹ lọ sin òkú obinrin ẹni ègún yìí nítorí pé ọmọ ọba ni.” +Àwọn ọkunrin tí wọ́n lọ sin òkú náà kò rí nǹkankan àfi agbárí, ati egungun ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀. +Nígbà tí wọ́n pada wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jehu, ó ní, “OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wolii Elija, iranṣẹ rẹ̀ pé, ajá ni yóo jẹ òkú Jesebẹli ní agbègbè Jesireeli. +Òkú rẹ̀ yóo fọ́n ká bí ìgbẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní lè dá a mọ̀ mọ́.” +Ọdọmọkunrin wolii náà bá lọ sí Ramoti Gileadi. +Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bá àwọn olórí ogun níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé. Ó wí pé, “Balogun, wọ́n rán mi níṣẹ́ sí ọ.”Jehu bá bèèrè pé, “Ta ni ninu wa?”Ọdọmọkunrin náà bá dáhùn pé, “Ìwọ ni, Balogun.” +Àwọn mejeeji bá jọ wọ inú yàrá lọ, ọdọmọkunrin wolii náà da òróró sí orí Jehu, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli, àwọn eniyan OLUWA.’ +O óo pa ìdílé oluwa rẹ, Ahabu ọba rẹ́, kí n lè gbẹ̀san lára Jesebẹli fún àwọn wolii mi ati àwọn iranṣẹ mi tí ó pa. +Gbogbo ìdílé Ahabu ni yóo ṣègbé, n óo sì pa gbogbo àwọn ọmọkunrin tí wọ́n wà ninu ìdílé náà, ati ẹrú ati ọmọ. +N óo ṣe ìdílé Ahabu bí mo ti ṣe àwọn ìdílé Jeroboamu ọmọ Nebati, ati ìdílé Baaṣa ọba, ọmọ Ahija. +A fi Òróró Yan Jehu ní Ọba Israẹli. +Èmi, Simoni Peteru iranṣẹ ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn tí wọn ní irú anfaani t�� a níláti gbàgbọ́ bíi tiwa, nípa òdodo Ọlọrun wa ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. +Ẹ̀yin ará, ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹ fi gbọdọ̀ túbọ̀ ní ìtara láti fi pípè tí a pè yín ati yíyàn tí a yàn yín hàn. Tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi, ẹ kò ní kùnà. +Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ti ṣe ní ẹ̀tọ́ láti rìn gaara wọ ìjọba ayérayé ti Oluwa wa, ati Olùgbàlà Jesu Kristi. +Nítorí náà ni mo ṣe pinnu pé n óo máa ran yín létí gbogbo nǹkan wọnyi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti mọ̀ wọ́n, ẹ sì ti fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu òtítọ́ tí ẹ ti mọ̀. +Nítorí mo kà á sí ẹ̀tọ́ mi, níwọ̀n ìgbà tí mo wà ninu àgọ́ ara yìí, láti ji yín ninu oorun nípa rírán yín létí. +Nítorí mo mọ̀ pé láìpẹ́ n óo bọ́ àgọ́ ara mi sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Oluwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí. +Ṣugbọn mò ń làkàkà pé nígbà tí mo bá lọ tán, kí ẹ ní ohun tí ẹ óo fi máa ṣe ìrántí nǹkan wọnyi nígbà gbogbo. +Kì í ṣe ìtàn àròsọ ni a gbójú lé nígbà tí a sọ fun yín nípa agbára ati wíwá Oluwa wa Jesu Kristi, ṣugbọn ẹlẹ́rìí ọlá ńlá rẹ̀ ni a jẹ́. +Nítorí a rí i nígbà tí ó gba ọlá ati ògo lọ́dọ̀ Ọlọrun Baba, nígbà tí ó gbọ́ ohùn láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ọlá ati ògo yẹ fún, tí ó wí pé,“Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi,inú mi dùn sí ọ.” +Àwa fúnra wa gbọ́ ohùn yìí nígbà tí ó wá láti ọ̀run nítorí a wà pẹlu rẹ̀ lórí òkè mímọ́ nígbà náà. +A tún rí ẹ̀rí tí ó dájú ninu àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wolii, pé, kí ẹ ṣe akiyesi ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ó dàbí fìtílà tí ń tàn ninu òkùnkùn, títí ilẹ̀ yóo fi mọ̀, títí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóo fi tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sinu ọkàn yín. +Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia pọ̀ sí i fun yín nípa mímọ Ọlọrun ati Jesu Oluwa wa. +Ṣugbọn kí ẹ kọ́kọ́ mọ èyí pé, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kan ninu Ìwé Mímọ́ tí ẹnìkan lè dá túmọ̀. +Nítorí kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ ẹnikẹ́ni ni àsọtẹ́lẹ̀ kan fi wá, nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ni àwọn eniyan fi ń sọ ọ̀rọ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Oluwa wá. +Nípa agbára Ọlọrun tí kì í ṣe ti eniyan, ó ti fún wa ní ohun gbogbo tí yóo jẹ́ kí á gbé irú ìgbé-ayé tí ó dára ati ti ìwà-bí-Ọlọrun, nípa mímọ ẹni tí ó fi ògo ati ọlá rẹ̀ pè wá. +Nípasẹ̀ èyí ni a ti gba àwọn ìlérí iyebíye tí ó tóbi jùlọ, tí ó fi jẹ́ pé ẹ ti di alábàápín ninu ìwà Ọlọrun, ẹ sì ti sá fún ìbàjẹ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti mú wọ inú ayé. +Nítorí èyí, kí ẹ ní ìtara láti fi ìwà ọmọlúwàbí kún igbagbọ yín, kí ẹ sì fi ìmọ̀ kún ìwà ọmọlúwàbí. +Ẹ fi ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀, kí ẹ fi ìgboyà kún ìkóra-ẹni-níjàánu, kí ẹ sì fi ìfọkànsìn kún ìgboyà. +Ẹ fi ìṣoore fún àwọn onigbagbọ kún ìfọkànsìn, kí ẹ sì fi ìfẹ́ kún ìṣoore fún àwọn onigbagbọ. +Nítorí tí ẹ bá ní àwọn nǹkan wọnyi; tí wọn ń dàgbà ninu yín, ìgbé-ayé yín kò ní jẹ́ lásán tabi kí ó jẹ́ aláìléso ninu mímọ Jesu Kristi. +Afọ́jú ni ẹni tí kò bá ní àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ kò ríran jìnnà, kò sì lè ronú ẹ̀yìn-ọ̀la. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti gbàgbé ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́. +Ìkíni. +Ṣugbọn bí àwọn wolii èké ti dìde láàrin àwọn eniyan Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùkọ́ni èké yóo wà láàrin yín. Wọn óo fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mú ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ wọ ààrin yín. Wọn óo sẹ́ Oluwa wọn tí ó rà wọ́n pada, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wọn óo mú ìparun wá sórí ara wọn kíákíá. +Pàápàá jùlọ, yóo jẹ àwọn tí wọn ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́rùn níyà. Wọ́n ń fojú tẹmbẹlu àwọn aláṣẹ.Ògbójú ni wọ́n, ati onigbeeraga; wọn kò bẹ̀rù láti sọ ìsọkúsọ sí àwọn ogun ọ̀run. +Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn angẹli tí wọ́n ní agbára ati ipá ju eniyan lọ, kò jẹ́ sọ ìsọkúsọ sí wọn nígbà tí wọn bá ń mú wọn lọ fún ìdájọ́ Ọlọrun. +Wọ́n dàbí ẹranko tí kò lè ronú, tí a bí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá, tí a mú, tí a pa. Wọn a máa sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ohun tí kò yé wọn. Ìparun yóo bá wọn ninu ọ̀nà ìparun wọn. +Ibi ni wọn yóo jèrè lórí ibi tí wọn ń ṣe. Wọ́n ka ati máa ṣe àríyá ní ọ̀sán gangan sí ìgbádùn. Àbùkù ati ẹ̀gàn ni wọ́n láàrin yín. Ẹ̀tàn ni àríyá tí wọn ń ṣe nígbà tí ẹ bá jọ jókòó láti jẹun. +Ojú wọn kún fún àgbèrè, kì í sinmi fún ẹ̀ṣẹ̀. Wọn a máa tan àwọn tí kò lágbára. Gbogbo ohun tí ó wà lórí ẹ̀mí wọn ni pé kí wọ́n ṣá rí owó lọ́nàkọnà. Ọmọ ègún ni wọ́n. +Wọ́n fi ọ̀nà títọ́ sílẹ̀, wọ́n ń ṣe ránun-rànun kiri. Wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, tí ó fẹ́ràn èrè aiṣododo. +Ṣugbọn tí ó rí ìbáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ẹranko tí kò lè fọhùn sọ̀rọ̀ bí eniyan, ó dí wolii náà lọ́wọ́ ninu ìwà aṣiwèrè rẹ̀. +Wọ́n dàbí ìsun omi tí ó ti gbẹ, ati ìkùukùu tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri. Ọlọrun ti pèsè ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri fún wọn. +Ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà lásán, tí kò ní ìtumọ̀, ní ń ti ẹnu wọn jáde. Nípa ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ati ìwà ìbàjẹ́ wọn, wọ́n ń tan àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kúrò láàrin ìwà ìtànjẹ ti ẹgbẹ́ wọ́n àtijọ́ jẹ. +Wọ́n ṣèlérí òmìnira fún àwọn eniyan, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹrú ohun ìbàjẹ́ wọn ni àwọn fúnra wọn jẹ́, nítorí tí ohunkohun bá ti borí eniyan, olúwarẹ̀ di ẹrú nǹkan náà. +Ọpọlọpọ eniyan ni yóo bá wọn kẹ́gbẹ́ ninu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn; nítorí ìṣe wọn, àwọn eniyan yóo máa gan ọ̀nà òtítọ́. +Nítorí bí wọ́n bá ti bọ́ lọ́wọ́ ìbàjẹ́ ayé nípa mímọ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi, tí wọ́n tún wá pada sí ìwà àtijọ́, tí ìwà yìí bá tún borí wọn, ìgbẹ̀yìn wọn á wá burú ju ipò tí wọ́n wà lákọ̀ọ́kọ́ lọ. +Nítorí ó sàn fún wọn kí wọn má mọ ọ̀nà òdodo ju pé kí wọn wá mọ̀ ọ́n tán kí wọn wá yipada kúrò ninu òfin mímọ́ tí a ti fi kọ́ wọn. +Àwọn ni òtítọ́ òwe yìí ṣẹ mọ́ lára pé, “Ajá tún pada lọ kó èébì rẹ̀ jẹ.” Ati òwe kan tí wọn máa ń pa pé, “Ẹlẹ́dẹ̀ tí wọ́n fọ̀ nù yóo tún pada lọ yíràá ninu ẹrọ̀fọ̀.” +Wọn óo fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín nítorí ojúkòkòrò, kí wọ́n lè fi yín ṣe èrè jẹ. Ìdájọ́ tí ó wà lórí wọn láti ìgbà àtijọ́ kò parẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìparun tí ń bọ̀ wá bá wọn kò sùn. +Nítorí Ọlọrun kò dáríjì àwọn angẹli tí ó ṣẹ̀ ẹ́, ṣugbọn ó jù wọ́n sinu ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri ní ọ̀run àpáàdì títí di ọjọ́ ìdájọ́. +Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò dáríjì àwọn ará àtijọ́, nígbà tí ó fi ìkún omi pa ayé run pẹlu àwọn tí wọn kò bẹ̀rù rẹ̀, àfi Noa, ọ̀kan ninu àwọn mẹjọ, tí ń waasu òdodo, ni ó gbà là. +Bẹ́ẹ̀ tún ni ìlú Sodomu ati Gomora tí ó dá lẹ́bi, tí ó sì dáná sun. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọrun. +Ṣugbọn ó yọ Lọti tí ó jẹ́ olódodo eniyan, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí ìwàkiwà àwọn tí ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. +Nítorí ohun tí ojú rẹ̀ ń rí ati ohun tí etí rẹ̀ ń gbọ́ ń ba ọkàn ọkunrin olódodo yìí jẹ́ lojoojumọ bí ó ti ń gbé ààrin àwọn eniyan burúkú yìí. +Oluwa mọ ọ̀nà láti yọ àwọn olùfọkànsìn kúrò ninu ìdánwò, ṣugbọn ó pa àwọn alaiṣododo mọ́ de ìyà Ọjọ́ Ìdájọ́. +Àwọn Wolii Èké ati Olùkọ́ni Èké. +Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, èyí ni ìwé keji tí mo kọ si yín. Ninu ìwé mejeeji, mò ń ji yín pẹ́pẹ́, láti ran yín létí àwọn ohun tí ẹ mọ̀, kí ẹ lè fi ọkàn tòótọ́ rò wọ́n jinlẹ̀. +Ṣugbọn bí olè ni ọjọ́ Oluwa yóo dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parẹ́ pẹlu ariwo ńlá bí ìgbà tí iná ńlá bá ń jó ìgbẹ́. Àwọn ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo fò, wọ́n óo sì jóná. Ayé ati gbogbo nǹkan inú rẹ̀ yóo wá wà ní ìhòòhò. +Nígbà tí ìparun ń bọ̀ wá bá gbogbo nǹkan báyìí, irú ìgbé-ayé wo ni ó yẹ kí ẹ máa gbé? Ẹ níláti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀ ati olùfọkànsìn, +kí ẹ máa retí ọjọ́ Ọlọrun, kí ẹ máa ṣe akitiyan pé kí ó tètè dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parun, gbogbo ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo yọ́ ninu iná. +Gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, à ń dúró de àwọn ọ̀run titun ati ayé titun níbi tí òdodo yóo máa wà. +Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, nígbà tí ẹ̀ ń retí nǹkan wọnyi, ẹ máa ní ìtara láti wà láì lábùkù ati láì lábàwọ́n, kí ẹ wà ní alaafia pẹlu Ọlọrun. +Ẹ fi í sọ́kàn pé ìdí tí Oluwa wa fi mú sùúrù ni pé kí á lè ní ìgbàlà, bí Paulu arakunrin wa àyànfẹ́ ti kọ̀wé si yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún un. +Ninu gbogbo àwọn ìwé rẹ̀, nǹkankan náà ní ó ń sọ nípa ọ̀rọ̀ wọnyi. Ninu àwọn ìwé wọnyi, àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn le. Àwọn òpè ati àwọn tí wọn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ a máa yí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pada sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń yí àwọn ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yòókù. +Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, a ti kìlọ̀ fun yín tẹ́lẹ̀. Ẹ ṣọ́ra kí àwọn eniyan burúkú wọnyi má baà tàn yín sí inú ìṣìnà wọn, kí ẹ má baà ṣubú lórí ìpìlẹ̀ tí ��� dúró sí. +Ṣugbọn ẹ máa dàgbà ninu oore-ọ̀fẹ́ ati ìmọ̀ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi. Tirẹ̀ ni ògo nisinsinyii ati títí laelae. Amin. +Ẹ ranti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ ati òfin Oluwa wa ati Olùgbàlà tí ẹ gbà lọ́wọ́ aposteli yín. +Ní àkọ́kọ́, kí ẹ mọ èyí pé ní ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn tí wọn óo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà yóo wá, tí wọn óo máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. +Wọn óo máa sọ pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí ìlérí pé Jesu tún ń pada bọ̀? Nítorí láti ìgbà tí àwọn baba wa ninu igbagbọ ti lọ tán, bákan náà ni gbogbo nǹkan rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé!” +Nítorí wọ́n fi ojú fo èyí dá pé, láti ìgbà àtijọ́ ni àwọn ọ̀run ti wà, ati pé láti inú omi ni ilẹ̀ ti jáde nípa àṣẹ Ọlọrun. +Omi kan náà ni Ọlọrun fi pa ayé tí ó ti wà rí run. +Ṣugbọn àṣẹ kan náà ni Ọlọrun fi pa àwọn ọ̀run ati ayé ti àkókò yìí mọ́ kí ó lè dáná sun ún, ó ń fi wọ́n pamọ́ títí di ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí a óo pa àwọn eniyan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun run. +Ẹ̀yin ará, ẹ má fi ojú fo èyí dá, pé níwájú Oluwa ọjọ́ kan dàbí ẹgbẹrun ọdún, ẹgbẹrun ọdún sì dàbí ọjọ́ kan. +Oluwa kò jáfara nípa ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti rò, ṣugbọn ó ń mú sùúrù fun yín ni. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé ṣugbọn ó fi ààyè sílẹ̀ kí gbogbo eniyan lè ronupiwada. +Ìlérí Pé Oluwa Yóo tún Pada Wá. +Lẹ́yìn ikú Saulu, nígbà tí Dafidi pada dé láti ojú ogun, níbi tí ó ti ṣẹgun àwọn ará Amaleki, ó dúró ní ìlú Sikilagi fún ọjọ́ meji. +Mo bá súnmọ́ Saulu, mo sì pa á. Nítorí mo mọ̀ pé, tí ó bá kúkú ṣubú lulẹ̀, yóo kú náà ni. Mo bá ṣí adé orí rẹ̀, mo sì bọ́ ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ rẹ̀. Àwọn ni mo kó wá fún ọ yìí, Dafidi, oluwa mi.” +Ni Dafidi ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn. +Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; nítorí Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan OLUWA nítorí pé ọpọlọpọ wọn ni wọ́n ti pa lójú ogun. +Dafidi bèèrè lọ́wọ́ ọdọmọkunrin tí ó wá ròyìn fún un pé, “Níbo ni o ti wá?”Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ará Amaleki kan, tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli ni mí.” +Dafidi tún bi í pé, “Báwo ni ẹ̀rù kò ṣe bà ọ́ láti pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn?” +Ni Dafidi bá pàṣẹ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, lọ pa ọdọmọkunrin ará Amaleki náà. Ọkunrin náà bá pa á. +Dafidi wí fún ọdọmọkunrin ará Amaleki náà pé, “Ìwọ ni o fa èyí sí orí ara rẹ. Ìwọ ni o dá ara rẹ lẹ́bi, nípa jíjẹ́wọ́ pé, ìwọ ni o pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn.” +Dafidi bá kọ orin arò fún Saulu, ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, +ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ àwọn eniyan Juda ní orin náà. (Àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà ninu ) Orin arò náà lọ báyìí: +“A! Israẹli, wọ́n ti pa àwọn tí o fi ń ṣògo lórí àwọn òkè rẹ!Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú! +Ní ọjọ́ kẹta, ọdọmọkunrin kan wá, láti inú àgọ́ Saulu, ó ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sí orí, láti fi ìbànújẹ́ hàn. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. +Ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀ ní Gati,ẹ má ṣe ròyìn rẹ̀ ní ìgboro Aṣikeloni;kí inú àwọn obinrin Filistini má baà dùn,kí àwọn ọmọbinrin àwọn aláìkọlà má baà máa yọ̀. +“Ẹ̀yin òkè Giliboa,kí òjò má ṣe rọ̀ le yín lórí,bẹ́ẹ̀ ni kí ìrì má ṣe sẹ̀ sórí yín,kí èso kan má so mọ́ ní gbogbo orí òkè Giliboa,nítorí pé, ibẹ̀ ni apata àwọn akikanju ti dípẹtà;a kò sì fi òróró kun apata Saulu mọ́. +Ọrun Jonatani kì í pada lásán,bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í pada,láì fi ẹnu kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ó pa,ati ọ̀rá àwọn akikanju. +“Saulu ati Jonatani,àyànfẹ́ ati eniyan rere,wọn kì í ya ara wọn nígbà ayé wọn,nígbà tí ikú sì dé,wọn kò ya ara wọn.Wọ́n yára ju àṣá lọ,wọ́n sì lágbára ju kinniun lọ. +“Ẹ̀yin obinrin Israẹli,ẹ sọkún nítorí Saulu,ẹni tí ó ro yín ní aṣọ elése àlùkò,tí ó sì fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́. +“Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú lójú ogun!Jonatani ti ṣubú lulẹ̀,wọ́n ti pa á lórí òkè. +“Mò ń ṣe ìdárò rẹ,Jonatani arakunrin mi;o ṣọ̀wọ́n fún mi lọpọlọpọ.Ìfẹ́ tí o ní sí mi, kò ṣe é fi ẹnu sọ,ó ju ìfẹ́ obinrin lọ. +“Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú,tí àwọn ohun ìj�� ogun sì ń ṣègbé!” +Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Láti inú àgọ́ àwọn ọmọ Israẹli ni mo ti sá àsálà.” +Dafidi wí fún un pé, “Sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún mi.”Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Sísá ni àwọn ọmọ ogun Israẹli sá kúrò lójú ogun, ọpọlọpọ ninu wọn ni wọ́n sì ti pa; wọ́n ti pa Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ pẹlu.” +Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ ti kú?” +Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Orí òkè Giliboa ni mo wà, ni mo déédé rí Saulu tí ó fara ti ọ̀kọ̀ rẹ̀. Mo sì rí i tí kẹ̀kẹ́ ogun àwọn ọ̀tá ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ń lépa rẹ̀. +Bí ó ti bojú wẹ̀yìn, tí ó rí mi, ó pè mí. Mo sì dá a lóhùn pé, ‘Èmi nìyí.’ +Ó bi mí pé, ta ni mí; mo dá a lóhùn pé, ‘Ọ̀kan ninu àwọn ará Amaleki ni mí.’ +Saulu bá wí fún mi pé, ‘Sún mọ́ mi níhìn-ín, kí o pa mí, nítorí pé mo ti fara gbọgbẹ́, mò ń jẹ̀rora gidigidi, ṣugbọn ẹ̀mí mi ṣì wà sibẹ.’ +Dafidi Gbọ́ nípa Ikú Saulu. +Lẹ́yìn èyí, ni Nahaṣi, ọba Amoni kú, Hanuni, ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè. +Ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yòókù sábẹ́ ọ̀gágun Abiṣai, tí ó jẹ́ arakunrin rẹ̀, Abiṣai bá fi olukuluku sí ipò rẹ̀, wọ́n dojú kọ àwọn ará Amoni. +Joabu wí fún un pé, “Bí o bá rí i pé àwọn ará Siria fẹ́ ṣẹgun mi, wá ràn mí lọ́wọ́. Bí èmi náà bá sì rí i pé àwọn ará Amoni fẹ́ ṣẹgun rẹ, n óo wá ràn ọ́ lọ́wọ́. +Múra gírí, jẹ́ kí á fi gbogbo agbára wa jà fún àwọn eniyan wa ati fún ìlú Ọlọrun wa. Kí OLUWA wa ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.” +Joabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tẹ̀síwájú láti gbógun ti àwọn ará Siria, àwọn ará Siria sì sá. +Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ará Siria ń sá lọ, àwọn náà sá fún Abiṣai, wọ́n sì pada sinu ìlú. Joabu bá pada lẹ́yìn àwọn ará Amoni, ó sì lọ sí Jerusalẹmu. +Nígbà tí àwọn ará Siria rí i pé, àwọn ọmọ ogun Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ. +Hadadeseri ọba, bá ranṣẹ sí àwọn ará Siria tí wọ́n wà ní ìhà ìlà oòrùn odò Yufurate, wọ́n bá wá sí Helamu. Ṣobaki tí ó jẹ́ balogun àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, ni aṣiwaju wọn. +Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó kó gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, ó la odò Jọdani kọjá lọ sí Helamu. Olukuluku àwọn ará Siria dúró ní ipò wọn, wọ́n dojú kọ Dafidi, wọ́n sì bá a jagun. +Àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ọmọ ogun Siria pada, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ pa ẹẹdẹgbẹrin (700) ninu àwọn tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ogun Siria, ati ọ̀kẹ́ meji (40,000) ninu àwọn ẹlẹ́ṣin wọn. Wọ́n ṣá Ṣobaki tí ó jẹ́ balogun wọn lọ́gbẹ́, ó sì kú sójú ogun. +Nígbà tí àwọn ọba tí wọ́n wà lẹ́yìn Hadadeseri rí i pé, àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n bá Israẹli làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Láti ìgbà náà ni ẹ̀rù sì ti ń ba àwọn ará Siria láti ran àwọn ará Amoni lọ́wọ́. +Dafidi ọba wí pé, “N óo ṣe ẹ̀tọ́ fún Hanuni, ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe ẹ̀tọ́ fún mi.” Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti tù ú ninu, nítorí ikú baba rẹ̀.Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Dafidi dé Amoni, +àwọn àgbààgbà ìlú náà wí fún Hanuni ọba wọn pé, “Ṣé o rò pé baba rẹ ni Dafidi bu ọlá fún tóbẹ́ẹ̀, tí ó fi rán àwọn oníṣẹ́ láti wá tù ọ́ ninu? Rárá o! Amí ni ó rán wọn wá ṣe, kí wọ́n lè wo gbogbo ìlú wò, kí ó baà lè ṣẹgun wa.” +Hanuni bá ki àwọn oníṣẹ́ Dafidi mọ́lẹ̀, ó fá apá kan irùngbọ̀n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, ó gé aṣọ wọn ní déédé ìbàdí, ó sì tì wọ́n jáde. +Ìtìjú bá wọn tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò lè pada sílé. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ranṣẹ sí wọn pé kí wọ́n dúró ní Jẹriko títí tí irùngbọ̀n wọn yóo fi hù, kí wọ́n tó máa pada bọ̀. +Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ti di ọ̀tá Dafidi, wọ́n ranṣẹ lọ fi owó gba ọ̀kẹ́ kan (20,000) jagunjagun ninu àwọn ará Siria tí wọ́n ń gbé Betirehobu ati Soba. Wọ́n gba ẹgbẹrun (1,000) lọ́dọ̀ ọba Maaka ati ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn ará Tobu. +Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó rán Joabu ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, láti lọ gbógun tì wọ́n. +Àwọn ará Amoni jáde sí àwọn ọmọ ogun Israẹli, wọ́n tò sí ẹnubodè wọn ní Raba, tíí ṣe olú ìlú wọn. Gbogbo àwọn ọmọ ogun, ará Siria tí wọ́n wá láti Soba ati Rehobu, ati àwọn ará Tobu ati ti Maaka, àwọn dá dúró ninu pápá. +Nígbà tí Joabu rí i pé àwọn ọ̀tá yóo gbógun ti àwọn níwájú ati lẹ́yìn, ó yan àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli, ó ní kí wọ́n dojú kọ àwọn ará Siria. +Dafidi Ṣẹgun Àwọn Ará Amoni ati Àwọn Ará Siria. +Ní àkókò ìgbà tí igi ń rúwé, tí ó jẹ́ àkókò tí gbogbo àwọn ọba máa ń lọ sójú ogun, Dafidi rán Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun Israẹli jáde. Wọ́n ṣẹgun àwọn ará Amoni, wọ́n sì dó ti ìlú Raba, ṣugbọn Dafidi dúró ní Jerusalẹmu. +Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “O ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ìrìn àjò dé ni, kí ló dé tí o kò lọ sí ilé rẹ?” +Uraya dá a lóhùn pé, “Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Juda wà lójú ogun, àpótí ẹ̀rí OLUWA sì wà pẹlu wọn. Joabu balogun mi ati àwọn ọ̀gágun wà lójú ogun, níbi tí wọ́n pàgọ́ sí ní ìta gbangba, ṣé ó yẹ kí n lọ sílé, kí n máa jẹ, kí n máa mu, kí n sì sùn ti aya mi? Níwọ̀n ìgbà tí o wà láyé, tí o sì wà láàyè, n kò jẹ́ dán irú rẹ̀ wò.” +Dafidi dá a lóhùn pé, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ dúró níhìn-ín títí di ọ̀la, n óo sì rán ọ pada. Uraya bá dúró ní Jerusalẹmu, ní ọjọ́ náà ati ọjọ́ keji. +Dafidi pè é kí ó wá bá òun jẹ oúnjẹ alẹ́ ọjọ́ náà, ó sì fún un ní ọtí mu yó, ṣugbọn Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, orí aṣọ òtútù rẹ̀ ni ó sùn, pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ ninu ilé ìṣọ́ ọba, ní ààfin. +Nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Dafidi kọ ìwé kan sí Joabu, ó sì fi rán Uraya. +Ìwé náà kà báyìí pé, “Fi Uraya sí iwájú ogun, níbi tí ogun ti gbóná girigiri. Lẹ́yìn náà, kí ẹ dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀, kí ogun lè pa á.” +Nítorí náà, nígbà tí Joabu dóti ìlú Raba, ó rán Uraya lọ sí ibi tí ó mọ̀ pé àwọn ọ̀tá ti lágbára gidigidi. +Àwọn ọmọ ogun àwọn ọ̀tá jáde láti inú ìlú láti bá àwọn ọmọ ogun Joabu jà. Wọ́n pa ninu àwọn ọ̀gágun Dafidi, wọ́n sì pa Uraya ará Hiti náà. +Joabu bá ranṣẹ sí Dafidi láti ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lójú ogun fún un. +Ó sọ fún oníṣẹ́ tí ó rán pé, “Bí o bá ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lójú ogun fún ọba tán, +Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, nígbà tí Dafidi jí lójú oorun, ó gun orí òrùlé ààfin rẹ̀. Bí ó ti ń rìn káàkiri níbẹ̀, ó rí obinrin kan tí ń wẹ̀, obinrin náà jẹ́ arẹwà gidigidi. +inú lè bí i, kí ó sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi súnmọ́ ìlú náà tóbẹ́ẹ̀ láti bá wọn jà? Ẹ ti gbàgbé pé wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí ta ọfà láti orí ògiri wọn ni? +Ẹ ti gbàgbé bí wọ́n ti ṣe pa Abimeleki ọmọ Gideoni? Ṣebí obinrin kan ni ó ju ọlọ ata sílẹ̀ láti orí ògiri ní Tebesi, tí ó sì pa á. Kí ló dé tí ẹ fi súnmọ́ ògiri tóbẹ́ẹ̀?’ Bí ọba bá bèèrè irú ìbéèrè yìí, sọ fún un pé, ‘Wọ́n ti pa Uraya, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun rẹ̀ pẹlu.’ ” +Oníṣẹ́ náà bá tọ Dafidi lọ, ó sì ròyìn fún un gẹ́gẹ́ bí Joabu ti rán an pé kí ó sọ. +Ó ní, “Àwọn ọ̀tá wa lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde láti inú ìlú wọn láti bá wa jà ninu pápá, ṣugbọn a lé wọn pada títí dé ẹnubodè ìlú wọn. +Àwọn tafàtafà bẹ̀rẹ̀ sí ta ọfà sí wa láti orí ògiri wọn, wọ́n sì pa ninu àwọn ọ̀gágun rẹ, wọ́n pa Uraya náà pẹlu.” +Dafidi rán oníṣẹ́ náà sí Joabu pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí da ọkàn rẹ rú níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ẹnikẹ́ni kò lè mọ ẹni tí ogun yóo pa. Tún ara mú gidigidi, kí o sì gba ìlú náà.” +Nígbà tí Batiṣeba gbọ́ pé wọ́n ti pa ọkọ òun, ó ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. +Nígbà tí àkókò ọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, Dafidi ní kí wọ́n mú un wá sí ààfin, Batiṣeba sì di aya rẹ̀. Ó bí ọmọkunrin kan fún un, ṣugbọn inú OLUWA kò dùn sí ohun tí Dafidi ṣe. +Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ, láti wádìí aya ẹni tí obinrin náà í ṣe. Ẹnìkan sì sọ fún un pé Batiṣeba ọmọ Eliamu ni, aya Uraya, ará Hiti. +Dafidi bá ranṣẹ lọ pè é. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bá a lòpọ̀. Batiṣeba sì ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ètò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tí ó parí nǹkan oṣù rẹ̀ ni. Ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀. +Nígbà tí ó yá, ó rí i pé òun lóyún, ó sì rán oníṣẹ́, pé kí wọ́n sọ fún Dafidi ọba. +Dafidi bá ranṣẹ sí Joabu, pé kí ó fi Uraya ará Hiti ranṣẹ sí òun, Joabu sì fi ranṣẹ sí Dafidi. +Nígbà tí Uraya dé, Dafidi bèèrè alaafia Joabu ati ti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó bèèrè bí ogun ti ń lọ sí. +Lẹ́yìn náà, ó wí fún Uraya pé, “Máa lọ sí ilé rẹ kí o sì sinmi fún ìgbà díẹ̀.” Uraya kúrò lọ́dọ̀ ọba, Dafidi sì di ẹ̀bùn ranṣẹ sí i. +Ṣugbọn Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀, ó sùn sí ẹnu ọ̀nà ààfin pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba tí ń ṣọ́ ààfin. +Dafidi ati Batiṣeba. +OLUWA rán Natani wolii sí Dafidi. Natani bá tọ Dafidi lọ, ó sì sọ fún un pé, “Àwọn ọkunrin meji wà ninu ìlú kan, ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, ekeji sì jẹ́ talaka. +Nítorí náà, ogun kò ní kúrò ní ìdílé rẹ títí lae; nítorí pé o ti kẹ́gàn mi, o sì ti gba aya Uraya. +Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Wò ó! N óo jẹ́ kí ẹnìkan ninu ìdílé rẹ ṣe ibi sí ọ. Ojú rẹ ni yóo ṣe tí n óo fi fi àwọn aya rẹ fún ẹlòmíràn, tí yóo sì máa bá wọn lòpọ̀ ní ọ̀sán gangan. +Níkọ̀kọ̀ ni o dá ẹ̀ṣẹ̀ yìí, ṣugbọn níwájú gbogbo Israẹli, ní ọ̀sán gangan, ni n óo ṣe ohun tí mò ń sọ yìí.’ ” +Dafidi bá dáhùn pé, “Mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA.”Natani dá a lóhùn pé, “OLUWA ti dáríjì ọ́, o kò sì ní kú. +Ṣugbọn nítorí pé ohun tí o ṣe yìí jẹ́ àfojúdi sí OLUWA, ọmọ tí ó bí fún ọ yóo kú.” +Natani bá lọ sí ilé rẹ̀.OLUWA fi àìsàn ṣe ọmọ tí aya Uraya bí fún Dafidi. +Dafidi bá ń gbadura sí Ọlọrun pé kí ara ọmọ náà lè yá, ó ń gbààwẹ̀, ó sì ń sùn lórí ilẹ̀ lásán ní alaalẹ́. +Àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀ rọ̀ ọ́, pé kí ó dìde nílẹ̀, ṣugbọn ó kọ̀, kò sì bá wọn jẹ nǹkankan. +Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà kú, ẹ̀rù sì ba àwọn iranṣẹ Dafidi láti sọ fún un pé ọmọ ti kú. Wọ́n ní, “Ìgbà tí ọmọ yìí wà láàyè, a bá Dafidi sọ̀rọ̀, kò dá wa lóhùn. Báwo ni a ṣe fẹ́ sọ fún un pé ọmọ ti kú? Ó lè pa ara rẹ̀ lára.” +Nígbà tí Dafidi rí i pé wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ó fura pé ọmọ ti kú. Ó bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé ọmọ ti kú ni?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ó ti kú.” +Ọkunrin ọlọ́rọ̀ yìí ní ọpọlọpọ agbo mààlúù, ati agbo aguntan. +Dafidi bá dìde kúrò ní ilẹ̀, ó wẹ̀, ó fi òróró pa ara rẹ̀, ó pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì lọ sí ilé OLUWA láti jọ́sìn. Lẹ́yìn náà, ó pada sí ilé rẹ̀, ó bèèrè fún oúnjẹ, wọ́n gbé e fún un, ó sì jẹ ẹ́. +Àwọn iranṣẹ rẹ̀ bi í pé, “Kabiyesi, ọ̀rọ̀ yìí rú wa lójú, kí ni ohun tí ò ń ṣe yìí? Nígbà tí ọmọ yìí wà láàyè, ò ń gbààwẹ̀, ò ń sọkún nítorí rẹ̀. Ṣugbọn gbàrà tí ó kú tán, o dìde o sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹun!” +Dafidi dá wọn lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí ó wà láàyè, mo gbààwẹ̀, mo sì sọkún, pé bóyá OLUWA yóo ṣàánú mi, kí ó má kú. +Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti kú, kí ni n óo tún máa gbààwẹ̀ sí? Ṣé mo lè jí i dìde ni? Èmi ni n óo tọ̀ ọ́ lọ, kò tún lè pada tọ̀ mí wá mọ́.” +Dafidi bá tu Batiṣeba, aya rẹ̀ ninu, ó bá a lòpọ̀, ó sì bí ọmọkunrin kan fún un. Dafidi sọ ọmọ yìí ní Solomoni. OLUWA fẹ́ràn ọmọ náà, +ó sì rán Natani wolii pé kí ó sọ ọmọ náà ní Jedidaya, nítorí pé, OLUWA fẹ́ràn rẹ̀. +Ní gbogbo àkókò yìí, Joabu wà níbi tí ó ti gbógun ti Raba, olú ìlú àwọn ará Amoni, ó sì gba ìlú ọba wọn. +Ó ranṣẹ sí Dafidi láti ròyìn fún un pé, “Mo ti gbógun ti Raba, mo sì ti gba ìlú tí orísun omi wọn wà, +kó àwọn ọmọ ogun yòókù jọ, kí o kọlu ìlú náà, kí o sì gbà á fúnra rẹ. N kò fẹ́ gba ìlú náà kí ògo gbígbà rẹ̀ má baà jẹ́ tèmi.” +Dafidi bá kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó lọ sí Raba, ó gbógun tì í, ó sì ṣẹgun rẹ̀. +Ṣugbọn ọkunrin talaka yìí kò ní nǹkankan, àfi ọmọ aguntan kékeré kan tí ó rà, tí ó sì ń tọ́jú títí tí ó fi dàgbà ninu ilé rẹ̀, pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ninu oúnjẹ tí òun pàápàá ń jẹ ni ó ti ń fún un jẹ, igbá tí ọkunrin yìí fi ń mu omi ni ó fi ń bu omi fún ọmọ aguntan rẹ̀ mu. A sì máa gbé e jókòó lórí ẹsẹ̀, bí ẹni pé ọmọ rẹ̀ gan-an ni. +Dafidi ṣí adé wúrà orí ọba wọn, adé náà wọ̀n tó ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, ó sì ní òkúta olówó iyebíye kan lára, ó sì fi dé orí ara rẹ̀. Dafidi kó ọpọlọpọ àwọn ìkógun mìíràn ninu ìlú náà. +Ó bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo àwọn ará ìlú náà ṣiṣẹ́. Àwọn kan ń lo ayùn, àwọn mìíràn ń lo ọkọ́ onírin, ati àáké onírin, àwọn mìíràn sì ń gé bulọọku, wọ́n ń sun ún. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sí àwọn ará ìlú Amoni yòókù. Lẹ́yìn náà, òun ati àwọn eniyan rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu. +Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, àlejò dé bá ọkunrin olówó ninu ilé rẹ̀. Ọkunrin yìí kò fẹ́ fọwọ́ kan èyíkéyìí ninu ẹran tirẹ̀ láti pa ṣe àlejò náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹyọ ọmọ aguntan kan tí talaka yìí ní, ni olówó yìí gbà, tí ó sì pa ṣe àlejò.” +Nígbà tí Dafidi gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú bí i gidigidi sí ọkunrin ọlọ́rọ̀ náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi OLUWA Alààyè búra pé ẹni tí ó dán irú rẹ̀ wò, kíkú ni yóo kú. +Ó sì níláti san ìlọ́po mẹrin ọmọ aguntan tí ó gbà pada, nítorí nǹkan burúkú tí ó ṣe, ati nítorí pé kò ní ojú àánú. +Natani bá dá Dafidi lóhùn pé, “Ìwọ gan-an ni ẹni náà. Ohun tí OLUWA Ọlọrun Israẹli sì ní kí n wí fún ọ nìyí; ó ní, ‘Mo fi ọ́ jọba lórí Israẹli, mo sì gbà ọ́ kúrò lọ́wọ́ Saulu. +Mo fún ọ ní ilé oluwa rẹ ati àwọn aya rẹ̀. Mo fi ọ́ jọba lórí Israẹli ati Juda. Ati pé, bí èyí kò bá tó ọ, ǹ bá fún ọ ní ìlọ́po meji rẹ̀. +Kí ló dé tí o fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ OLUWA, tí o sì ṣe nǹkan burúkú yìí níwájú rẹ̀. Ìwọ ni o fi Uraya fún ogun pa; tí o jẹ́ kí àwọn Amoni pa á. Lẹ́yìn náà, o gba aya rẹ̀. +Iṣẹ́ tí Natani Jẹ́ ati Ìrònúpìwàdà Dafidi. +Absalomu ọmọ Dafidi ní arabinrin kan tí ó jẹ́ arẹwà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari. Dafidi tún ní ọmọkunrin mìíràn tí ń jẹ́ Amnoni. Amnoni yìí fẹ́ràn Tamari lọpọlọpọ. +Amnoni bá sọ fún un pé, “Gbé e tọ̀ mí wá ninu yàrá mi, kí o sì gbé e kalẹ̀ níwájú mi.” Tamari bá gbé àkàrà náà, ó sì tọ Amnoni lọ láti gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ̀ ninu yàrá. +Bí ó ti ń gbé e fún un, ni Amnoni gbá a mú, ó wí fún un pé, “Wá, mo fẹ́ bá ọ lòpọ̀.” +Tamari dáhùn pé, “Rárá, má fi ipá mú mi, nítorí ẹnìkan kò gbọdọ̀ dán irú rẹ̀ wò ní Israẹli, má hùwà òmùgọ̀; +níbo ni mo fẹ́ fi ojú sí láàrin gbogbo eniyan? Ohun ìtìjú patapata ni yóo sì jẹ́ fún ìwọ náà ní Israẹli. Jọ̀wọ́, bá ọba sọ̀rọ̀, mo mọ̀ dájúdájú pé yóo fi mí fún ọ.” +Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò gbọ́ ohun tí Tamari sọ fún un. Nígbà tí ó sì jẹ́ pé Amnoni lágbára jù ú lọ, ó fi tipátipá bá a lòpọ̀. +Lẹ́yìn náà, Amnoni kórìíra rẹ̀ gidigidi. Ìkórìíra náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó tún wá ju bí ó ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ lọ. Ó ní kí ó bọ́ sóde, kí ó máa lọ. +Tamari dá a lóhùn pé, “Rárá, arakunrin mi, lílé tí ò ń lé mi jáde yìí burú ju ipá tí o fi bá mi lòpọ̀ lọ.”Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò gbọ́ tirẹ̀. +Kàkà bẹ́ẹ̀, Amnoni pe iranṣẹ rẹ̀ kan, ó wí fún un pé, “Mú obinrin yìí jáde kúrò níwájú mi, tì í sóde, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” +Iranṣẹ náà bá ti Tamari jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.Aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ alápá gígùn, irú èyí tí àwọn ọmọ ọba, obinrin, tí kò tíì wọlé ọkọ máa ń wọ̀, ni Tamari wọ̀. +Tamari bá ku eérú sí orí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó káwọ́ lórí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún bí ó ti ń lọ. +Amnoni fẹ́ràn rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó di àìsàn sí i lára. Wundia ni Tamari, kò tíì mọ ọkunrin rí; nítorí náà ó dàbí ẹni pé kò ṣeéṣe fún Amnoni láti bá a ṣe nǹkankan. +Nígbà tí Absalomu, ẹ̀gbọ́n Tamari, rí i, ó bi í léèrè pé, “Ṣé Amnoni bá ọ lòpọ̀ ni? Jọ̀wọ́, arabinrin mi, gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ọmọ baba kan náà ni ẹ̀yin mejeeji, nítorí náà, má sọ fún ẹnikẹ́ni.” Tamari bá ń gbé ilé Absalomu. Òun nìkan ni ó dá wà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ pupọ. +Nígbà tí Dafidi ọba gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí i gidi. +Absalomu kórìíra Amnoni gan-an nítorí pé ó fi ipá bá Tamari, àbúrò rẹ̀, lòpọ̀, ṣugbọn kò bá a sọ nǹkankan; ìbáà ṣe rere ìbáà sì ṣe burúkú. +Lẹ́yìn ọdún meji tí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀, Absalomu lọ rẹ́ irun aguntan rẹ̀ ní Baali Hasori, lẹ́bàá ìlú Efuraimu, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba patapata lọkunrin sibẹ. +Ó lọ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ọba, ó wí fún un pé, “Kabiyesi, iranṣẹ rẹ ń rẹ́ irun aguntan rẹ̀, mo sì fẹ́ kí kabiyesi ati gbogbo àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá síbi àjọ̀dún náà.” +Ọba ní, “Rárá, ọmọ mi, bí gbogbo wa bá lọ, wahala náà yóo pọ̀jù fún ọ.” Absalomu rọ ọba títí, ṣugbọn ó kọ̀ jálẹ̀. Ọba bá súre fún un, ó ní kí ó máa lọ. +Absalomu dáhùn pé, “Ó dára, bí o kò bá lè lọ, ṣé o óo jẹ́ kí Amnoni arakunrin mi lọ?”Ọba bá bèèrè pé, “Nítorí kí ni yóo ṣe ba yín lọ?” +Ṣugbọn Absalomu rọ Dafidi títí tí ó fi gbà pé kí Amnoni ati àwọn ọmọ ọba yòókù lọkunrin bá a lọ.Absalomu sì se àsè rẹpẹtẹ, bí ẹni pé ọba ni ó fẹ́ ṣe lálejò. +Absalomu wí fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ máa kíyèsí Amnoni, nígbà tí ó bá mu ọtí yó, bí mo bá ti fun yín ní àṣẹ pé kí ẹ pa á, pípa ni kí ẹ pa á, ẹ má bẹ̀rù; èmi ni mo ran yín. Ẹ mú ọkàn gírí kí ẹ sì ṣe bí akikanju.” +Àwọn iranṣẹ náà bá tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀, wọ́n sì pa Amnoni. Gbogbo àwọn ọmọ Dafidi yòókù bá gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì sá lọ. +Ṣugbọn Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin Dafidi. Jonadabu yìí jẹ́ alárèékérekè eniyan. +Nígbà tí wọn ń sá bọ̀ wálé, àwọn kan wá sọ fún Dafidi pé, “Absalomu ti pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ, ati pé kò ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan.” +Ọba dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó sì sùn sórí ilẹ̀ lásán, àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ fa aṣọ tiwọn náà ya. +Ṣugbọn Jonadabu, ọmọ Ṣimea, arakunrin Dafidi, wí fún ọba pé, “Kabiyesi, ẹnikẹ́ni kò pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ. Amnoni nìkan ni Absalomu pàṣẹ pé kí wọ́n pa. Láti ìgbà tí Amnoni ti fi ipá bá Tamari, arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, ni ó ti pinnu láti ṣe ohun tí ó ṣe yìí. +Nítorí náà, kí oluwa mi má gba ìròyìn tí wọ́n mú wá gbọ́, pé gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n ti kú. Amnoni nìkan ni wọ́n pa.” +Absalomu sá lọ ní àkókò yìí.Kò pẹ́ rárá, lẹ́yìn náà, ọmọ ogun tí ń ṣọ́ ọ̀nà tí ó wọ ìlú rí ogunlọ́gọ̀ eniyan, wọ́n ń bọ̀ láti ọ̀nà Horonaimu, lẹ́bàá òkè. +Jonadabu bá sọ fún ọba pé, “Àwọn ọmọ oluwa mi ni wọ́n ń bọ̀ yìí, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí.” +Ó fẹ́rẹ̀ má tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, tí àwọn ọmọ Dafidi fi wọlé, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, Dafidi ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ náà sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. +Ṣugbọn Absalomu sá lọ sọ́dọ̀ Talimai, ọmọ Amihudu, ọba Geṣuri, Dafidi sì ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ lojoojumọ. +Absalomu wà ní Geṣuri níbi tí ó sá lọ fún ọdún mẹta. +Nígbà tí ó yá tí Dafidi gbé ìbànújẹ́ ikú Amnoni ọmọ rẹ̀ kúrò lára, ọkàn Absalomu ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fà á. +Ní ọjọ́ kan, ó bèèrè lọ́wọ́ Amnoni pé, “Ṣebí ọmọ ọba ni ọ́, kí ló dé tí ò ń rù lojoojumọ? Sọ fún mi.”Amnoni dá a lóhùn pé, “Ìfẹ́ Tamari, àbúrò Absalomu, arakunrin mi, ni ó wọ̀ mí lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀.” +Jonadabu dáhùn, ó ní, “Lọ dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ, kí o sì ṣe bí ẹni pé ara rẹ kò yá. Nígbà tí baba rẹ bá wá bẹ̀ ọ́ wò, wí fún un pé, kí ó jọ̀wọ́ kí ó jẹ́ kí Tamari arabinrin rẹ wá fún ọ ní oúnjẹ. Sọ fún un pé, o fẹ́ kí ó wá se oúnjẹ náà lọ́dọ̀ rẹ níbi tí o ti lè máa rí i, kí ó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ gbé e fún ọ.” +Amnoni bá dùbúlẹ̀, ó ṣe bí ẹni tí ó ń ṣàìsàn.Nígbà tí Dafidi ọba lọ bẹ̀ ẹ́ wò, Amnoni wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari, arabinrin mi, wá ṣe àkàrà díẹ̀ lọ́dọ̀ mi níhìn-ín, níbi tí mo ti lè máa rí i, kí ó sì gbé e wá fún mi.” +Dafidi bá ranṣẹ pe Tamari ninu ààfin, ó ní kí ó lọ sinu ilé Amnoni, kí ó lọ tọ́jú oúnjẹ fún un. +Tamari lọ, ó bá Amnoni lórí ibùsùn níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí. Ó bu ìyẹ̀fun díẹ̀, ó pò ó, ó gé e ní ìwọ̀n àkàrà bíi mélòó kan, níbi tí Amnoni ti lè máa rí i. Lẹ́yìn náà, ó gbé e sórí iná títí tí ó fi jinná, +ó sì dà á sinu àwo kan, ó gbé e fún un. Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò jẹ ẹ́, ó ní kí ó sọ fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ilé kí wọ́n jáde, gbogbo wọn bá jáde. +Amnoni ati Tamari. +Joabu, ọmọ Seruaya, ṣe akiyesi pé ọkàn Absalomu ń fa Dafidi pupọ. +Ọba dá a lóhùn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá tún halẹ̀ mọ́ ọ, mú olúwarẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi, kò sì ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́ laelae.” +Obinrin yìí tún wí fún ọba pé, “Kabiyesi, jọ̀wọ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ kí ẹni tí ó fẹ́ gbẹ̀san ikú ọmọ mi kinni má baà pa ọmọ mi keji.”Dafidi ọba bá dáhùn pé, “Mo ṣèlérí fún ọ, ní orúkọ OLUWA Ọlọrun alààyè, pé, ẹnikẹ́ni kò ní ṣe ọmọ rẹ ní ohunkohun.” +Obinrin yìí bá tún dáhùn pé, “Kabiyesi, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n sọ gbolohun kan yìí sí i.”Ọba dáhùn pé, “Ó dára, mò ń gbọ́.” +Obinrin náà wí pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe ohun tí ó burú yìí sí àwọn eniyan Ọlọrun? Ọ̀rọ̀ tí o sọ tán nisinsinyii, ara rẹ gan-an ni o fi dá lẹ́bi, nítorí pé, o kò jẹ́ kí ọmọ rẹ pada wá sílé láti ibi tí ó sá lọ? +Dájúdájú, gbogbo wa ni a óo kú. A dàbí omi tí ó dà sílẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò sì lè kójọ mọ́. Ẹni tí ó bá ti kú, Ọlọrun pàápàá kì í tún gbé e dìde mọ́, ṣugbọn kabiyesi lè wá ọ̀nà, láti fi mú ẹni tí ó bá sá jáde kúrò ní ìlú pada wálé. +Kabiyesi, ìdí tí mo fi kó ọ̀rọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá ni pé, àwọn eniyan ń dẹ́rùbà mí, èyí ni ó mú kí n rò ninu ara mi pé, n óo wá bá ọ sọ̀rọ̀, mo sì ní ìrètí pé, kabiyesi yóo ṣe ohun tí mo wá bẹ̀bẹ̀ pé kí ó bá mi ṣe. +Mo mọ̀ pé ọba yóo fetí sílẹ̀ láti gbọ́ tèmi, yóo sì gbà mí kalẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ pa èmi ati ọmọ mi, tí ó sì fẹ́ pa wá run kúrò lórí ilẹ̀ tí Ọlọrun fún àwọn eniyan rẹ̀. +Mo sì ti mọ̀ lọ́kàn ara mi pé, ọ̀rọ̀ tí kabiyesi bá sọ fún mi yóo fi mí lọ́kàn balẹ̀ nítorí pé, ọba dàbí angẹli Ọlọrun tí ó mọ ìyàtọ̀ láàrin ire ati ibi. OLUWA Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀.” +Ọba dá obinrin náà lóhùn pé, “Ọ̀rọ̀ kan ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ rẹ, mo sì fẹ́ kí o sọ òtítọ́ rẹ̀ fún mi.”Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bèèrè ohunkohun tí o bá fẹ́.” +Ọba bá bí i pé, “Ṣé Joabu ni ó rán ọ ní gbogbo iṣẹ́ tí o wá jẹ́ yìí, àbí òun kọ?”Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bí o ti bèèrè ìbéèrè yìí kò jẹ́ kí n mọ̀ bí mo ti lè yí ẹnu pada rárá. Òtítọ́ ni, Joabu ni ó kọ́ mi ní gbogbo ohun tí mo sọ, ati gbogbo bí mo ti ṣe. +Nítorí náà, ó ranṣẹ sí ọlọ́gbọ́n obinrin kan, tí ń gbé Tekoa. Nígbà tí obinrin yìí dé, Joabu wí fún un pé, “Ṣe bí ẹni pé o wà ninu ọ̀fọ̀, wọ aṣọ ọ̀fọ̀, má fi òróró para, kí o sì fi irun rẹ sílẹ̀ játijàti. Ṣe bí ẹni tí ó ti wà ninu ọ̀fọ̀ fún ọjọ́ pípẹ́; +Ṣugbọn, òun náà fẹ́ tún nǹkan ṣe, ni ó fi ṣe ohun tí ó ṣe. Ṣugbọn kabiyesi ní ọgbọ́n bí angẹli Ọlọ́run, láti mọ ohun gbogbo lórí ilẹ̀ ayé.” +Nígbà náà ni ọba sọ fún Joabu pé, “Mo ti pinnu láti ṣe ohun tí o fẹ́ kí n ṣe. Lọ, kí o sì mú Absalomu, ọmọ mi, pada wá.” +Joabu bá wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ọba, ó ní, “Kabiyesi, nisinsinyii ni èmi iranṣẹ rẹ mọ̀ pé mo ti bá ojurere rẹ pàdé, nítorí pé o ṣe ohun tí mo fẹ́.” +Joabu bá gbéra, ó lọ sí Geṣuri, ó sì mú Absalomu pada wá sí Jerusalẹmu. +Ṣugbọn ọba pàṣẹ pé kí Absalomu máa gbé ilé rẹ̀, nítorí pé òun kò fẹ́ rí i sójú. Nítorí náà, inú ilé Absalomu ni ó ń gbé, kò sì dé ọ̀dọ̀ ọba rárá. +Kò sí ẹyọ ẹnìkan ní gbogbo Israẹli tí òkìkí ẹwà rẹ̀ kàn bí ti Absalomu. Kò sí àbùkù kankan rárá lára rẹ̀ bí ti í wù kó mọ, láti orí títí dé àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀. +Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni í máa ń gé irun orí rẹ̀, nígbà tí ó bá kún, tí ó sì gùn ju bí ó ti yẹ lọ. Tí wọ́n bá fi ìwọ̀n ọba wọn èyí tí wọ́n bá gé lára irun rẹ̀, a máa tó igba ṣekeli. +Absalomu bí ọmọkunrin mẹta ati ọmọbinrin kan. Tamari ni orúkọ ọmọbinrin yìí, ó sì jẹ́ arẹwà. +Ọdún meji ni Absalomu fi gbé Jerusalẹmu láì fi ojú kan ọba. +Ní ọjọ́ kan, ó ranṣẹ sí Joabu, pé kí ó wá mú òun lọ sọ́dọ̀ ọba, ṣugbọn Joabu kọ̀, kò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Absalomu ranṣẹ pe Joabu lẹẹkeji, Joabu sì tún kọ̀, kò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. +kí o lọ sọ́dọ̀ ọba, kí o sì sọ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí fún un.” Joabu bá kọ́ ọ ní ohun tí yóo wí. +Absalomu bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Oko Joabu wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tèmi, ó sì gbin ọkà baali sinu rẹ̀, ẹ lọ fi iná sí oko náà.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ti iná bọ oko Joabu. +Nígbà náà ni Joabu lọ sí ilé Absalomu, ó bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn iranṣẹ rẹ fi ti iná bọ oko mi?” +Absalomu dáhùn pé, “Nítorí pé mo ranṣẹ pè ọ́, pé kí o wá, kí n lè rán ọ lọ bèèrè lọ́wọ́ ọba pé, ‘Kí ni mo kúrò ní Geṣuri tí mo sì wá síhìn-ín fún? Ìbá sàn kí n kúkú wà lọ́hùn-ún.’ Mo fẹ́ kí o ṣe ètò kí n lè fi ojú kan ọba, bí ó bá sì jẹ́ pé mo jẹ̀bi, kí ó pa mí.” +Joabu bá tọ Dafidi ọba lọ, ó sì sọ ohun tí Absalomu wí fún un. Ọba ranṣẹ pe Absalomu, ó sì wá sọ́dọ̀ ọba. Ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ọba bá fi ẹnu kò ó ní ẹnu. +Obinrin ará Tekoa náà bá tọ ọba lọ, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó wí fún un báyìí pé, “Kabiyesi, gbà mí.” +Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni o fẹ́?”Ó dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, opó ni mí, ọkọ mi ti kú. +Ọmọkunrin meji ni mo bí. Ní ọjọ́ kan, àwọn mejeeji ń bá ara wọn jà ninu pápá, kò sì sí ẹnikẹ́ni nítòsí láti là wọ́n, ni ọ̀kan ninu wọn bá lu ekeji rẹ̀ pa. +Nisinsinyii, kabiyesi, gbogbo àwọn eniyan mi ni wọ́n ti kẹ̀yìn sí mi. W��̣n ní dandan kí ń fa ọmọ mi kan yòókù kalẹ̀ fún àwọn, kí wọ́n lè pa á nítorí arakunrin rẹ̀ tí ó pa. Bí mo bá gbà fún wọn, kò ní sí ẹni tí yóo jogún ọkọ mi, wọn yóo já ìrètí mi kan tí ó kù kulẹ̀, kò sì ní sí ọmọkunrin tí yóo gbé orúkọ ọkọ mi ró, tí orúkọ náà kò fi ní parun.” +Ọba dá a lóhùn pé, “Máa pada lọ sí ilé rẹ, n óo mójú tó ọ̀rọ̀ náà.” +Obinrin náà wí fún ọba pé, “Kabiyesi, gbogbo ohun tí o bá ṣe nípa ọ̀rọ̀ yìí, èmi ati ìdílé mi ni a ni ẹ̀bi rẹ̀, ẹ̀bi rẹ̀ kò kan kabiyesi ati ìdílé rẹ̀ rárá.” +Joabu Ṣe Ètò Àtipadà Absalomu. +Lẹ́yìn èyí, Absalomu wá kẹ̀kẹ́ ogun kan, ati àwọn ẹṣin, ati aadọta ọkunrin tí wọn yóo máa sáré níwájú rẹ̀. +Ṣugbọn Absalomu rán iṣẹ́ àṣírí sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ó ní, “Tí ẹ bá gbọ́ tí wọ́n fọn fèrè, kí ẹ sọ pé, ‘Absalomu ti di ọba ní Heburoni.’ ” +Igba ọkunrin ni Absalomu pè, tí wọ́n sì bá a lọ láti Jerusalẹmu. Wọn kò ní èrò ibi lọ́kàn, ní tiwọn, wọn kò sì mọ ohun tí ó wà lọ́kàn Absalomu. +Nígbà tí Absalomu ń rúbọ lọ́wọ́, ó ranṣẹ sí ìlú Gilo láti lọ pe Ahitofeli ará Gilo, ọ̀kan ninu àwọn olùdámọ̀ràn Dafidi ọba. Ọ̀tẹ̀ tí Absalomu ń dì ń gbilẹ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ náà ń pọ̀ sí i. +Oníṣẹ́ kan wá ròyìn fún Dafidi pé, “Ọkàn gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti ṣí sí ọ̀dọ̀ Absalomu.” +Dafidi bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Jerusalẹmu pé, “A gbọdọ̀ sá lọ lẹsẹkẹsẹ, bí a kò bá fẹ́ bọ́ sọ́wọ́ Absalomu. Ẹ ṣe gírí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo bá wa, yóo ṣẹgun wa, yóo sì pa ìlú yìí run.” +Àwọn iranṣẹ rẹ̀ dáhùn pé, “Kabiyesi, ohunkohun tí o bá wí ni a óo ṣe.” +Ọba bá jáde kúrò ní ìlú, gbogbo ìdílé rẹ̀, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ṣugbọn ọba fi mẹ́wàá ninu àwọn obinrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa bojútó ààfin. +Bí ọba ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ti ń jáde kúrò ní ìlú, wọ́n dúró níbi ilé tí ó wà ní ìpẹ̀kun ìlú. +Gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì ń tò kọjá níwájú rẹ̀; àwọn ẹgbẹta (600) ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e láti Gati náà tò kọjá níwájú rẹ̀. +Ọba bá kọjú sí Itai ará Gati, ó sì bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá wa lọ? Pada, kí o lọ dúró ti ọba, àlejò ni ọ́, sísá ni o sá kúrò ní ìlú rẹ wá síhìn-ín. +A máa jí ní òwúrọ̀ kutukutu, a sì dúró ní ẹ̀bá ọ̀nà, ní ẹnu ibodè ìlú. Nígbàkúùgbà tí ẹnikẹ́ni bá ń mú ẹjọ́ bọ̀ wá sọ́dọ̀ ọba, Absalomu á pe olúwarẹ̀ sọ́dọ̀, á bi í pé, “Níbo ni o ti wá?” Lẹ́yìn ìgbà tí ẹni náà bá sọ inú ẹ̀yà tí òun ti wá fún Absalomu tán, +Kò sì tíì pẹ́ pupọ tí o dé, kí ló dé tí o fi fẹ́ máa bá mi káàkiri ninu ìrìnkèrindò mi? Èmi gan-an nìyí, n kò tíì mọ ibi tí mò ń lọ. Pada kí àwọn ará ìlú rẹ gbogbo sì máa bá ọ lọ. OLUWA yóo fẹ́ràn ìwọ náà, yóo sì dúró tì ọ́.” +Ṣugbọn Itai dáhùn pé, “Kabiyesi, mo fi OLUWA búra, bí ẹ̀mí oluwa mi ọba tí ń bẹ láàyè, pé, ibikíbi tí o bá ń lọ ni n óo máa bá ọ lọ, kì báà tilẹ̀ já sí ikú.” +Dafidi dáhùn, ó ní, “Kò burú.” Itai ati àwọn eniyan rẹ̀, ati àwọn ọmọ kéékèèké, tò kọjá níwájú ọba. +Gbogbo ìlú bú sẹ́kún bí àwọn eniyan náà ti ń lọ. Ọba rékọjá odò Kidironi, àwọn eniyan rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Gbogbo wọ́n jọ ń lọ sí ọ̀nà apá ijù. +Sadoku, alufaa, wà láàrin wọn, àwọn ọmọ Lefi sì wà pẹlu rẹ̀, wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí lọ́wọ́. Wọ́n gbé e kalẹ̀ títí tí gbogbo àwọn eniyan náà fi jáde kúrò ní ìlú. Abiatari, alufaa náà wà láàrin wọn. +Ọba wí fún Sadoku pé, “Gbé Àpótí Ẹ̀rí náà pada sí ìlú. Bí inú OLUWA bá dùn sí mi, bí mo bá bá ojurere OLUWA pàdé, yóo mú mi pada, n óo tún fi ojú kan Àpótí Ẹ̀rí náà ati ilé OLUWA. +Ṣugbọn bí inú rẹ̀ kò bá dùn sí mi, kí ó ṣe mí bí ó bá ti tọ́ ní ojú rẹ̀.” +Ó tún fi kún un fún Sadoku pé, “Wò ó! Ìwọ ati Abiatari, ẹ pada sí ìlú ní alaafia, mú Ahimaasi, ọmọ rẹ, ati Jonatani ọmọ Abiatari lọ́wọ́. +N óo dúró ní ibi tí wọ́n ń gbà la odò kọjá ní ijù níhìn-ín, títí tí n óo fi rí oníṣẹ́ rẹ.” +Sadoku ati Abiatari bá gbé àpótí ẹ̀rí pada sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wà níbẹ̀. +Absalomu á wí fún un pé, “Wò ó, ẹjọ́ rẹ tọ́, o sì jàre, ṣugbọn ọba kò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ̀, láti máa gbọ́ irú ẹjọ́ báyìí.” +Ṣugbọn Dafidi gun gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi lọ, láì wọ bàtà, ó ń sọkún bí ó ti ń lọ, ó sì fi aṣọ bo orí rẹ̀ láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, tí wọ́n ń bá a lọ náà fi aṣọ bo orí wọn, wọ́n sì ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ. +Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé, Ahitofeli ti darapọ̀ mọ́ ọ̀tẹ̀ tí Absalomu ń dì, Dafidi gbadura sí OLUWA, ó ní, “Jọ̀wọ́, OLUWA, yí gbogbo ìmọ̀ràn tí Ahitofeli bá fún Absalomu pada sí asán.” +Nígbà tí Dafidi gun òkè náà dé orí, níbi tí wọ́n ti máa ń rúbọ sí Ọlọ́run, Huṣai, ará Ariki, wá pàdé rẹ̀ pẹlu aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya, ó sì ti ku eruku sí orí rẹ̀. +Dafidi wí fún un pé, “Bí o bá bá mi lọ, ìdíwọ́ ni o óo jẹ́ fún mi. +Bí o bá pada sí ìlú, tí o sì sọ fún Absalomu, ọba, pé o ti ṣetán láti sìn ín pẹlu ẹ̀mí òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí o ti sin èmi baba rẹ̀, nígbà náà ni o óo ní anfaani láti bá mi yí ìmọ̀ràn Ahitofeli po. +Ṣebí Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa mejeeji wà níbẹ̀, gbogbo ohun tí o bá ti gbọ́ ninu ààfin ọba ni kí o máa sọ fún wọn. +Àwọn ọmọ wọn mejeeji, Ahimaasi ati Jonatani wà lọ́dọ̀ wọn. Gbogbo ohun tí ẹ bá gbọ́, kí ẹ máa rán wọn sí mi.” +Huṣai bá pada, ó dé Jerusalẹmu bí Absalomu tí ń wọ ìlú bọ̀ gẹ́lẹ́. +Absalomu á tún wá fi kún un pé, “A! Bí wọ́n bá fi mí ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ yìí ni, bí ẹnikẹ́ni bá ní èdè-àìyedè kan pẹlu ẹlòmíràn, tabi tí ẹnìkan bá fẹ́ gba ohun tíí ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀, wọn ìbá máa tọ̀ mí wá, ǹ bá sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún wọn.” +Bí ẹnikẹ́ni bá súnmọ́ Absalomu láti wólẹ̀, kí ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, Absalomu á tètè na ọwọ́ sí i, á gbá a mú, a sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu. +Bẹ́ẹ̀ ni Absalomu máa ń ṣe sí gbogbo àwọn eniyan Israẹli, tí wọ́n bá kó ẹjọ́ wá sọ́dọ̀ ọba. Nítorí bí ó ti ń ṣe yìí, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n fẹ́ràn rẹ̀. +Ní ìparí ọdún kẹrin, Absalomu tọ Dafidi lọ, ó ní, “Kabiyesi, fún mi láàyè kí n lọ sí Heburoni. Mo fẹ́ lọ san ẹ̀jẹ́ kan tí mo jẹ́ fún OLUWA. +Nígbà tí mo fi wà ní Geṣuri, ní ilẹ̀ Siria, mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, pé bí ó bá mú mi pada sí Jerusalẹmu, n óo lọ sìn ín ní Heburoni.” +Ọba bá dá a lóhùn pé kí ó máa lọ ní alaafia, Absalomu bá dìde ó lọ sí Heburoni. +Absalomu Dìtẹ̀ mọ́ Dafidi. +Ní gẹ́rẹ́ tí Dafidi kọjá góńgó orí òkè náà, Siba, iranṣẹ Mẹfiboṣẹti pàdé rẹ̀, ó ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bíi mélòó kan bọ̀ tí ó di igba (200) burẹdi rù, pẹlu ọgọrun-un ṣiiri èso resini, ati ọgọrun-un ṣiiri èso tútù mìíràn ati àpò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini. +Ṣugbọn ọba dáhùn pé, “Kò sí ohun tí ó kan ẹ̀yin ọmọ Seruaya ninu ọ̀rọ̀ yìí. Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó sọ fún un pé kí ó máa ṣépè lé mi, ta ló ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè pé, kí ló dé tí ó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?” +Dafidi sọ fún Abiṣai ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣebí ọmọ tèmi gan-an ni ó ń gbìyànjú láti pa mí yìí, kí ló dé tí ọ̀rọ̀ ti ará Bẹnjamini yìí fi wá jọ yín lójú. OLUWA ni ó ní kí ó máa ṣépè, nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣẹ́ ẹ. +Bóyá OLUWA lè wo ìpọ́njú mi, kí ó sì fi ìre dípò èpè tí ó ń ṣẹ́ lé mi.” +Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ń bá tiwọn lọ, Ṣimei sì ń tẹ̀lé wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji òkè náà, bí ó ti ń tẹ̀lé wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè, ó ń sọ òkúta lù ú, ó sì ń da erùpẹ̀ sí wọn lára. +Nígbà tí ọba ati àwọn eniyan rẹ̀ yóo fi dé ibi odò Jọdani, ó ti rẹ̀ wọ́n, nítorí náà, wọ́n sinmi níbẹ̀. +Absalomu ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ wọ Jerusalẹmu lọ, Ahitofeli sì wà pẹlu wọn. +Nígbà tí Huṣai, ará Ariki, ọ̀rẹ́ Dafidi pàdé Absalomu, ó kígbe pé “Kí ọba kí ó pẹ́! Kí ọba kí ó pẹ́!” +Absalomu bá bi í pé, “Kí ló dé, tí o kò fi ṣe olótìítọ́ sí Dafidi ọ̀rẹ́ rẹ mọ́? Kí ló dé tí o kò fi bá a lọ?” +Huṣai dáhùn pé, “Ẹ̀yìn ẹnikẹ́ni tí OLUWA, ati àwọn eniyan wọnyi, ati gbogbo Israẹli bá yàn ni mo wà. Tirẹ̀ ni n óo jẹ́, n óo sì dúró tì í. +Ta ni ǹ bá tilẹ̀ tún sìn, bí kò ṣe ọmọ oluwa mi. Bí mo ti sin baba rẹ, bẹ́ẹ̀ gan-an ni n óo sin ìwọ náà.” +Dafidi ọba bi í pé, “Kí ni o fẹ́ fi gbogbo nǹkan wọnyi ṣe?” Siba dá a lóhùn pé, “Mo mú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnyi wá kí àwọn ìdílé Kabiyesi lè rí nǹkan gùn, mo mú burẹdi, ati èso wọnyi wá kí àwọn ọdọmọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lè rí nǹkan jẹ; ati ọtí waini, kí àwọn tí àárẹ̀ bá mú ninu aṣálẹ̀ lè rí nǹkan mu.” +Absalomu kọjú sí Ahitofeli, ó sì bi í pé, “Nígbà tí a ti dé Jerusalẹmu báyìí, kí ni ìmọ̀ràn rẹ?” +Ahitofeli dáhùn pé, “Wọlé lọ bá àwọn obinrin baba rẹ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa tọ́jú ààfin, kí o sì bá wọn lòpọ̀. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo wá gbà pé o ti kẹ̀yìn sí baba rẹ, ọkàn gbogbo àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ yóo sì balẹ̀.” +Wọ́n bá pàgọ́ kan fún Absalomu, lórí òrùlé ààfin, ó wọlé lọ bá àwọn obinrin baba rẹ̀ lójú gbogbo àwọn eniyan, ó sì bá wọn lòpọ̀. +Ní àkókò náà, ìmọ̀ràn tí Ahitofeli bá dá, ni àwọn eniyan máa ń gbà, bí ẹni pé Ọlọrun gan-an ni ó ń sọ̀rọ̀; Dafidi ati Absalomu pàápàá a máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn rẹ̀. +Ọba tún bi í pé, “Níbo ni Mẹfiboṣẹti, ọmọ ọmọ Saulu, ọ̀gá rẹ wà?”Siba dá a lóhùn pé, “Mẹfiboṣẹti dúró sí Jerusalẹmu; nítorí ó dá a lójú pé, nisinsinyii ni àwọn ọmọ Israẹli yóo dá ìjọba Saulu baba-baba rẹ̀ pada fún un.” +Ọba bá sọ fún Siba pé, “Gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Mẹfiboṣẹti di tìrẹ láti ìsinsìnyìí lọ.”Siba sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, mo júbà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n máa bá ojurere rẹ pàdé nígbà gbogbo.” +Nígbà tí Dafidi ọba dé Bahurimu, ọkunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera, láti inú ìdílé Saulu, jáde sí i, bí ó sì ti ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè lemọ́lemọ́. +Ó ń sọ òkúta lu Dafidi ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn eniyan ńláńlá ati ọpọlọpọ eniyan mìíràn wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji Dafidi ọba. +Ṣimei ń wí fún Dafidi bí ó ti ń ṣépè pé, “Kúrò lọ́dọ̀ mi! Kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìwọ apànìyàn ati eniyan lásán! +Ìwọ tí o gba ìjọba mọ́ Saulu lọ́wọ́, OLUWA ń jẹ ọ́ níyà nisinsinyii, fún ọpọlọpọ eniyan tí o pa ninu ìdílé Saulu. OLUWA sì ti fi ìjọba rẹ fún Absalomu, ọmọ rẹ, ìparun ti dé bá ọ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́.” +Abiṣai, ọmọ Seruaya wí fún ọba pé, “Kí ló dé tí òkú ajá lásánlàsàn yìí fi ń ṣépè lé ọba, oluwa mi? Jẹ́ kí n lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, kí n sì sọ orí rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní ọrùn rẹ̀.” +Dafidi ati Siba. +Lẹ́yìn náà, Ahitofeli wí fún Absalomu pé, “Jẹ́ kí n ṣa ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn ọmọ ogun, kí n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa Dafidi lọ lálẹ́ òní. +Nígbà náà, ẹ̀rù yóo ba àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì láyà bíi kinniun; nítorí pé, gbogbo eniyan ní Israẹli ni ó mọ̀ pé akọni jagunjagun ni baba rẹ, akikanju sì ni àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀. +Ìmọ̀ràn tèmi ni pé kí o kó gbogbo àwọn ọmọ ogun jọ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí wọ́n pọ̀ bíi yanrìn etí òkun. Ìwọ gan-an ni kí o ṣáájú wọn lọ sí ogun náà. +A óo kọlu Dafidi níbikíbi tí a bá ti bá a, a óo bò wọ́n bí ìgbà tí ìrì bá sẹ̀ sórí ilẹ̀; ẹnikẹ́ni kò sì ní yè ninu òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. +Bí ó bá sá wọ inú ìlú kan, àwọn ọmọ Israẹli yóo fi okùn fa ìlú náà lulẹ̀ sinu àfonífojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀. Ẹyọ òkúta kan ṣoṣo kò ní ṣẹ́kù sórí òkè náà.” +Absalomu ati gbogbo Israẹli dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn ti Huṣai dára ju ti Ahitofeli lọ,” nítorí pé OLUWA ti pinnu láti yí ìmọ̀ràn rere tí Ahitofeli mú wá pada, kí ibi lè bá Absalomu. +Huṣai bá lọ sọ fún Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa mejeeji, irú ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún Absalomu ati àwọn ọmọ Israẹli, ati èyí tí òun fún wọn. +Huṣai tún fi kún un pé, kí wọ́n ranṣẹ kíákíá lọ sọ fún Dafidi pé, kò gbọdọ̀ sùn níbi tí wọ́n ti ń ré odò Jọdani kọjá ninu aṣálẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Ó gbọdọ̀ kọjá sí òdìkejì odò lẹsẹkẹsẹ kí ọwọ́ má baà tẹ̀ ẹ́ ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì pa wọ́n. +Jonatani ati Ahimaasi dúró sí ibi orísun Enrogeli, ní ìgbèríko ati máa lọ sí Jerusalẹmu, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fojú kàn wọ́n, pé wọ́n wọ ìlú rárá. Iranṣẹbinrin kan ni ó máa ń lọ sọ ohun tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ fún wọn, àwọn náà á lọ sọ fún Dafidi. +Ṣugbọn ọmọkunrin kan rí wọn, ó sì sọ fún Absalomu. Jonatani ati Ahimaasi bá sáré lọ fi ara pamọ́ ní ilé ọkunrin kan ní Bahurimu. Ọkunrin yìí ní kànga kan ní àgbàlá ilé rẹ̀. Àwọn mejeeji bá kó sinu kànga náà. +Aya ọkunrin náà fi nǹkan dé e lórí, ó sì da ọkà bàbà lé e kí ẹnikẹ́ni má baà fura sí i. +N óo kọlù ú nígbà tí àárẹ̀ bá mú un; tí ọkàn rẹ̀ sì rẹ̀wẹ̀sì; ẹ̀rù yóo bà á, gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ yóo sì sá lọ. Ọba nìkan ṣoṣo ni n óo pa. +Nígbà tí àwọn iranṣẹ Absalomu dé ọ̀dọ̀ obinrin náà, wọ́n bi í pé, “Níbo ni Ahimaasi ati Jonatani wà?”Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti kọjá sí òdìkejì odò.”Àwọn ọkunrin náà wá wọn títí, ṣugbọn wọn kò rí wọn. Wọ́n bá pada lọ sí Jerusalẹmu. +Nígbà tí àwọn ọkunrin náà lọ tán, Ahimaasi ati Jonatani jáde ninu kànga, wọ́n sì lọ ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Dafidi. Wọ́n sọ ohun tí Ahitofeli ti gbèrò láti ṣe sí Dafidi. Wọ́n ní kí ó yára, kí ó rékọjá sí òdìkejì odò náà kíá. +Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Nígbà tí ilẹ̀ yóo fi mọ́, gbogbo wọn ti kọjá tán. +Nígbà tí Ahitofeli rí i pé, Absalomu kò tẹ̀lé ìmọ̀ràn tí òun fún un, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó pada lọ sí ìlú rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti ṣètò ilé rẹ̀, ó pokùnso, ó bá kú; wọ́n sì sin ín sí ibojì ìdílé rẹ̀. +Nígbà tí Absalomu ati àwọn ọmọ Israẹli yóo fi ré odò Jọdani kọjá tán, Dafidi ti dé ìlú tí wọn ń pè ní Mahanaimu. +Amasa ni Absalomu fi ṣe olórí ogun rẹ̀, dípò Joabu. Itira ará Iṣimaeli ni baba Amasa. Ìyá rẹ̀ sì ni Abigaili, ọmọbinrin Nahaṣi, arabinrin Seruaya, ìyá Joabu. +Absalomu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pàgọ́ sí ilẹ̀ Gileadi. +Nígbà tí Dafidi dé Mahanaimu, Ṣobi, ọmọ Nahaṣi, wá pàdé rẹ̀, láti ìlú Raba, ní ilẹ̀ Amoni. Makiri, ọmọ Amieli, náà wá, láti Lodebari; ati Basilai, láti Rogelimu, ní ilẹ̀ Gileadi. +Wọ́n kó ibùsùn lọ́wọ́ wá fún wọn, ati àwo, ìkòkò ati ọkà baali, ọkà tí wọ́n ti lọ̀, ati èyí tí wọ́n ti yan, erèé ati ẹ̀fọ́; +oyin, omi wàrà, ati wàrà sísè. Wọ́n sì kó aguntan wá pẹlu, láti inú agbo wọn fún Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀, kí wọ́n lè rí nǹkan jẹ. Nítorí wọ́n rò pé yóo ti rẹ̀ wọ́n, ebi yóo ti máa pa wọ́n, òùngbẹ yóo sì ti máa gbẹ wọ́n, ninu aṣálẹ̀ tí wọ́n wà. +N óo sì kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí iyawo tí ó lọ bá ọkọ rẹ̀ nílé. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni o fẹ́ pa, àwọn eniyan yòókù yóo sì wà ní alaafia.” +Ìmọ̀ràn náà dára lójú Absalomu ati gbogbo àgbààgbà Israẹli. +Ṣugbọn Absalomu dáhùn pé, “Ẹ pe Huṣai wá, kí á gbọ́ ohun tí òun náà yóo sọ.” +Nígbà tí Huṣai dé, Absalomu wí fún un pé, “Ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún wa nìyí, ṣé kí á tẹ̀lé e? Bí kò bá yẹ kí á tẹ̀lé e, sọ ohun tí ó yẹ kí á ṣe fún wa.” +Huṣai dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún Kabiyesi ní àkókò yìí, kò dára. +Ṣebí o mọ̀ pé, akikanju jagunjagun ni baba rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀? Ara kan wọ́n báyìí, wọn yóo sì rorò ju abo ẹkùn beari tí ọdẹ jí lọ́mọ kó lọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni jagunjagun tí ó ní ọpọlọpọ ìrírí ni baba rẹ, kò sì ní sùn lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní alẹ́ yìí. +Bóyá bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ninu ihò ilẹ̀ níbìkan ni ó wà tabi ibòmíràn. Bí Dafidi bá kọlu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì pa díẹ̀ ninu wọn, àwọn tí wọ́n bá gbọ́ yóo wí pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn eniyan Absalomu. +Huṣai Ṣi Absalomu lọ́nà. +Dafidi kó gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó pín wọn ní ọgọọgọrun-un (100) ati ẹgbẹẹgbẹrun (1,000), ó fi balogun kọ̀ọ̀kan ṣe olórí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan. +Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi rí i, ó bá lọ sọ fún Joabu pé òun rí Absalomu tí ó ń rọ̀ lórí igi Oaku. +Joabu dá a lóhùn pé, “Nígbà tí o rí i, kí ló dé tí o kò pa á níbẹ̀ lẹsẹkẹsẹ? Inú mi ìbá dùn láti fún ọ ní owó fadaka mẹ́wàá ati ìgbànú akikanju ninu ogun jíjà.” +Ṣugbọn ọmọ ogun náà dáhùn pé, “Ò báà tilẹ̀ fún mi ní ẹgbẹrun (1,000) owó fadaka, n kò ní ṣíwọ́ sókè pa ọmọ ọba. Gbogbo wa ni a gbọ́, nígbà tí ọba pàṣẹ fún ìwọ ati Abiṣai ati Itai pé, nítorí ti òun ọba, kí ẹ má pa Absalomu lára. +Tí mo bá ṣe àìgbọràn sí òfin ọba, tí mo sì pa Absalomu, ó pẹ́ ni, ó yá ni, ọba yóo gbọ́, bí ọba bá sì gbọ́, ìwọ gan-an kò ní gbà mí sílẹ̀.” +Joabu dáhùn pé, “N kò ní máa fi àkókò mi ṣòfò, kí n sọ pé mò ń bá ọ sọ̀rọ̀.” Joabu bá mú ọ̀kọ̀ mẹta, ó sọ wọ́n lu Absalomu ní igbá àyà lórí igi oaku tí ó há sí. +Mẹ́wàá ninu àwọn ọdọmọkunrin tí wọn ń ru ihamọra Joabu bá yí Absalomu po, wọ́n sì ṣá a pa. +Lẹ́yìn náà, Joabu fọn fèrè ogun, kí wọ́n dáwọ́ ogun jíjà dúró. Àwọn ọmọ ogun Dafidi bá pada lẹ́yìn àwọn ọmọ ogun Israẹli. +Wọ́n gbé òkú Absalomu jù sinu ihò jíjìn kan ninu igbó, wọ́n sì kó ọpọlọpọ òkúta jọ sórí òkú rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá sá, olukuluku gba ilé rẹ̀ lọ. +Nígbà ayé Absalomu, ó ṣe ọ̀wọ̀n ìrántí kan fún ara rẹ̀ ní àfonífojì ọba, nítorí kò ní ọmọkunrin kankan tí ó le gbé orúkọ rẹ̀ ró. Nítorí náà ni ó ṣe sọ ọ̀wọ̀n náà ní orúkọ ara rẹ̀; ọ̀wọ̀n Absalomu ni wọ́n ń pe ọ̀wọ̀n náà, títí di òní olónìí. +Ahimaasi, ọmọ Sadoku bá sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí n sáré tọ ọba lọ, kí n sì fún un ní ìròyìn ayọ̀ náà, pé OLUWA ti gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.” +Lẹ́yìn náà, ó rán wọn jáde ní ìpín mẹta, ó fi Joabu, ati Abiṣai, ọmọ Seruaya, àbúrò Joabu, ati Itai, ará Gati, ṣe ọ̀gágun àgbà ìpín kọ̀ọ̀kan. Ó ní òun pàápàá yóo bá wọn lọ. +Ṣugbọn Joabu dá a lóhùn pé, “Rárá o, kì í ṣe ìwọ ni o óo mú ìròyìn náà lọ lónìí, bí ó bá di ọjọ́ mìíràn, o lè mú ìròyìn ayọ̀ lọ. Kì í ṣe òní, nítorí pé ọmọ ọba ni ó kú.” +Joabu bá sọ fún ọ̀kan ninu àwọn ará Kuṣi pé, “Lọ sọ ohun tí o rí fún ọba.” Ará Kuṣi náà bá tẹríba fún Joabu, ó sì sáré lọ. +Ṣugbọn Ahimaasi ṣá tẹnu mọ́ ọn pé, “N kò kọ ohunkohun tí ó lè ṣẹlẹ̀, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n sáré tẹ̀lé ará Kuṣi náà lọ.”Joabu bi í pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ, ọmọ mi? Kò sí èrè kankan fún ọ níbẹ̀.” +Ahimaasi dáhùn pé, “Mo ṣá fẹ́ lọ ni, ohun yòówù tí ó lè ṣẹlẹ̀.”Joabu dáhùn pé, “Ǹjẹ́ bí o bá fẹ́, máa lọ.” Ahimaasi bá sáré gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì ṣáájú ará Kuṣi náà. +Dafidi wà ní àlàfo tí ó wà ní ààrin ẹnu ọ̀nà tinú ati ti òde, ní ẹnu ibodè ìlú. Ẹ̀ṣọ́ tí ń ṣọ́ bodè gun orí odi lọ, ó dúró lé orí òrùlé ẹnubodè. Bí ó ṣe gbé ojú sókè, ó rí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń sáré bọ̀. +Ó pe ọba nísàlẹ̀, ó sì sọ fún un, ọba bá dáhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ òun nìkan ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó ń mú bọ̀.” Ẹni tí ń sáré bọ̀ náà túbọ̀ ń súnmọ́ tòsí. +Ẹ̀ṣọ́ náà tún rí ẹyọ ẹnìkan, tí òun náà ń sáré bọ̀. Ó tún ké sí ẹ̀ṣọ́ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wò ó, ẹnìkan ni ó tún ń sáré bọ̀ yìí.”Ọba dáhùn pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni òun náà ń mú bọ̀.” +Ẹ̀ṣọ́ tún ní, “Ẹni tí ó ṣáájú tí mo rí yìí jọ Ahimaasi.”Ọba dáhùn pé, “Eniyan dáradára ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó sì ń mú bọ̀.” +Ahimaasi bá kígbe sókè pé, “Alaafia ni!” Ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú ọba, ó sì wí fún un pé, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ tí ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọba, oluwa mi.” +Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé nǹkankan kò ṣe Absalomu ọmọ mi?”Ahimaasi dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, nígbà tí Joabu fi ń rán mi bọ̀, gbogbo nǹkan dàrú, ó sì rí rúdurùdu, nítorí náà n kò lè sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an.” +Ṣugbọn wọ́n dá a lóhùn pé, “O kò ní bá wa lọ, nítorí pé bí a bá sá lójú ogun ní tiwa, tabi tí ìdajì ninu wa bá kú, kò jẹ́ ohunkohun fún àwọn ọ̀tá wa. Ṣugbọn ìwọ nìkan ju ẹgbaarun (10,000) wa lọ. Ohun tí ó dára ni pé kí o dúró ní ìlú, kí o sì máa fi nǹkan ranṣẹ sí wa láti fi ràn wá lọ́wọ́.” +Ọba bá ní kí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ kan ná, ó bá dúró. +Lẹ́yìn náà, ará Kuṣi náà dé, ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni mo mú wá fún oluwa mi, ọba! Nítorí pé, OLUWA ti fún ọ ní ìṣẹ́gun lónìí lórí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́.” +Ọba bi í pé, “Ṣé alaafia ni Absalomu, ọmọ mi wà?”Ará Kuṣi náà dáhùn pé, “Kí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Absalomu ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ, ati gbogbo àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọ.” +Ìbànújẹ́ ńlá dé bá ọba, ó bá gun òkè lọ sinu yàrá tí ó wà lókè ẹnu ọ̀nà ibodè, ó sì sọkún. Bí ó ti ń lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ké pé, “Ha! Ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Ọmọ mi! Kì bá ṣe pé ó ṣeéṣe ni, kí n kú dípò rẹ, Absalomu, ọmọ mi, ọmọ mi!” +Ọba dáhùn pé, “Ohunkohun tí ẹ bá ní kí n ṣe náà ni n óo ṣe.” Ọba bá dúró ní ẹnu ibodè, bí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ń tò kọjá lọ ní ọgọọgọrun-un (100) ati ẹgbẹẹgbẹrun (1,000). +Ó pàṣẹ fún Joabu, ati Abiṣai, ati Itai, ó ní, “Nítorí tèmi, ẹ má pa Absalomu lára.” Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì gbọ́ nígbà tí Dafidi ń pa àṣẹ yìí fún àwọn ọ̀gágun rẹ̀. +Àwọn ọmọ ogun náà bá jáde lọ sinu pápá láti bá àwọn ọmọ ogun Israẹli jà, ní aṣálẹ̀ Efuraimu. +Àwọn ọmọ ogun Dafidi ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Israẹli. Wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní ọjọ́ náà. Àwọn tí wọ́n kú lára wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000). +Ogun náà tàn káàkiri gbogbo agbègbè; àwọn tí wọ́n sì sọnù sinu igbó pọ̀ ju àwọn tí wọ́n fi idà pa lójú ogun lọ. +Lójijì, Absalomu já sí ààrin àwọn ọmọ ogun Dafidi. Ìbaaka ni Absalomu gùn. Ìbaaka yìí gba abẹ́ ẹ̀ka igi Oaku ńlá kan, ẹ̀ka igi yìí sì dí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi kọ́ Absalomu ní irun orí, Ìbaaka yọ lọ lábẹ́ rẹ̀, Absalomu sì ń rọ̀ dirodiro nítorí pé ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tólẹ̀. +Wọ́n Ṣẹgun Absalomu, Wọ́n sì Pa Á. +Àwọn kan lọ sọ fún Joabu pé, ọba ń sọkún, ó sì ń ṣọ̀fọ̀ Absalomu. +A fi àmì òróró yan Absalomu ní ọba, ṣugbọn wọ́n ti pa á lójú ogun, nítorí náà, ó yẹ kí ẹnìkan gbìyànjú láti mú Dafidi ọba pada.” +Ìròyìn ohun tí àwọn eniyan Israẹli ń wí kan Dafidi ọba lára. Dafidi ọba ranṣẹ sí àwọn alufaa mejeeji: Sadoku, ati Abiatari, láti bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà Juda pé, “Kí ló dé tí ẹ fi níláti gbẹ́yìn ninu ètò àtidá ọba pada sí ààfin rẹ̀? +Ṣebí ìbátan ọba ni yín, ẹ̀jẹ̀ kan náà sì ni yín? Kí ló dé tí ẹ fi níláti gbẹ́yìn ninu ètò àtidá ọba pada sí ààfin rẹ̀.” +Dafidi ní kí wọ́n sọ fún Amasa pé, ẹbí òun ni Amasa; ati pé, láti ìgbà náà lọ, Amasa ni òun yóo fi ṣe balogun òun, dípò Joabu. Ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá ṣe bẹ́ẹ̀. +Ọ̀rọ̀ tí Dafidi sọ yìí, mú kí àwọn eniyan Juda fara mọ́ ọn, wọ́n sì ranṣẹ sí i pé kí ó pada pẹlu gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀. +Nígbà tí ọba ń pada bọ̀, àwọn eniyan Juda wá sí Giligali láti pàdé rẹ̀ ati láti mú un kọjá odò Jọdani. +Ní àkókò yìí kan náà, Ṣimei, ọmọ Gera, ará Bẹnjamini, láti ìlú Bahurimu, sáré lọ sí odò Jọdani láti pàdé Dafidi ọba pẹlu àwọn eniyan Juda. +Ẹgbẹrun (1,000) eniyan, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ni ó kó lọ́wọ́. Siba, iranṣẹ ìdílé Saulu, náà wá pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀ mẹẹdogun, ati ogún iranṣẹ. Wọ́n dé sí etí odò kí ọba tó dé ibẹ̀. +Wọ́n rékọjá odò sí òdìkejì, láti dara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọn yóo sin ìdílé ọba kọjá odò, ati láti ṣe ohunkohun tí ọba bá fẹ́. Bí ọba ti múra láti kọjá odò náà, Ṣimei wólẹ̀ níwájú rẹ̀. +Ó ní, “Kabiyesi, jọ̀wọ́ má dá mi lẹ́bi, má sì ranti àṣìṣe tí mo ṣe ní ọjọ́ tí o kúrò ní Jerusalẹmu, jọ̀wọ́ gbàgbé rẹ̀. +Nítorí náà, ìṣẹ́gun ọjọ́ náà pada di ìbànújẹ́ fún gbogbo àwọn eniyan; nítorí wọ́n gbọ́ pé ọba ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀. +Mo mọ̀ pé mo ti ṣẹ̀; Ìdí nìyí, tí ó fi jẹ́ pé èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́ wá pàdé rẹ lónìí, ninu gbogbo ìdílé Josẹfu.” +Abiṣai ọmọ Seruaya dáhùn pé, “Pípa ni ó yẹ kí á pa Ṣimei nítorí pé ó ṣépè lé ẹni tí OLUWA fi òróró yàn ní ọba.” +Ṣugbọn Dafidi dá Abiṣai ati Joabu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lóhùn pé, “Kí ló kàn yín ninu ọ̀rọ̀ yìí? Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya, tí ẹ̀ ń ṣe bí ọ̀tá sí mi? Èmi ni ọba Israẹli lónìí, ẹnìkan kò sì ní pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli.” +Ó bá dá Ṣimei lóhùn, ó ní, “Mo búra fún ọ pé ẹnikẹ́ni kò ní pa ọ́.” +Lẹ́yìn náà, Mẹfiboṣẹti, ọmọ ọmọ Saulu, wá pàdé ọba. Láti ìgbà tí ọba ti kúrò ní Jerusalẹmu, títí tí ó fi pada dé ní alaafia, Mẹfiboṣẹti kò fọ ẹsẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò gé irùngbọ̀n rẹ̀, tabi kí ó fọ aṣọ rẹ̀. +Nígbà tí Mẹfiboṣẹti ti Jerusalẹmu dé láti pàdé ọba, ọba bi í pé, “Mẹfiboṣẹti, kí ló dé tí o kò fi bá mi lọ?” +Mẹfiboṣẹti dáhùn pé, “Kabiyesi, gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, arọ ni mí. Mo sọ fún iranṣẹ mi pé kí ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ní gàárì, kí n lè gùn ún tẹ̀lé ọ, ṣugbọn ó hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi. +Ó lọ pa irọ́ mọ́ mi lọ́dọ̀ ọba. Ṣugbọn bí angẹli Ọlọrun ni oluwa mi, ọba rí; nítorí náà, ṣe ohun tí ó bá tọ́ sí mi ní ojú rẹ. +Gbogbo ìdílé baba mi pátá ni ó yẹ kí o pa, ṣugbọn o gbà mí láàyè; o sì fún mi ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹun níbi tabili rẹ. Kò yẹ mí rárá, láti tún bèèrè nǹkankan mọ́ lọ́wọ́ kabiyesi.” +Ọba dá a lóhùn pé, “Má wulẹ̀ tún sọ nǹkankan mọ́, mo ti pinnu pé ìwọ ati Siba ni yóo pín gbogbo ogun Saulu.” +Àwọn ọmọ ogun náà yọ́ wọ ìlú jẹ́ẹ́, bí ẹni pé wọ́n sá lójú ogun, tí ìtìjú sì mú wọn. +Mẹfiboṣẹti bá dáhùn pé, “Jẹ́ kí Siba máa mú gbogbo rẹ̀, kìkì pé kabiyesi pada dé ilé ní alaafia ti tó fún mi.” +Basilai ará Gileadi náà wá láti Rogelimu. Ó bá ọba dé odò Jọdani láti sìn ín kọjá odò náà. +Basilai ti darúgbó gan-an, ẹni ọgọrin ọdún ni. Ó tọ́jú nǹkan jíjẹ fún ọba nígbà tí ó fi wà ní Mahanaimu, nítorí pé ọlọ́rọ̀ ni. +Ọba wí fún un pé, “Bá mi kálọ sí Jerusalẹmu, n óo sì tọ́jú rẹ dáradára.” +Ṣugbọn Basilai dáhùn pé, “Ọjọ́ tí ó kù fún mi láyé kò pọ̀ mọ́, kí ni n óo tún máa bá kabiyesi lọ sí Jerusalẹmu fún? +Mo ti di ẹni ọgọrin ọdún, kò sì sí ohunkohun tí ó tún wù mí mọ́. Oúnjẹ ati ohun mímu kò dùn lẹ́nu mi mọ́. Bí àwọn akọrin ń kọrin, n kò lè gbọ́ orin wọn mọ́. Wahala lásán ni n óo lọ kó bá oluwa mi, ọba. +Irú anfaani ńlá báyìí kò tọ́ sí mi láti ọ̀dọ̀ ọba, nítorí náà, n óo bá ọba gun òkè odò Jọdani, n óo sì bá ọ lọ sí iwájú díẹ̀ ni. +Lẹ́yìn náà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n pada lọ sí ilé mi, kí n lè kú sí ìlú mi, nítòsí ibojì àwọn òbí mi. Kimhamu ọmọ mi nìyí, jẹ́ kí ó máa bá ọ lọ, kí o sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ fún un.” +Ọba dáhùn pé, “N óo máa mú Kimhamu lọ, ohunkohun tí ó bá sì bèèrè, ni n óo ṣe fún un.” +Lẹ́yìn náà ni Dafidi ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ gòkè odò Jọdani. Ó kí Basilai, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì súre fún un; Basilai bá pada sí ilé rẹ̀. +Ọba dọwọ́ bojú, ó ń sọkún, ó sì ń kígbe sókè pé, “Ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi!” +Lẹ́yìn tí àwọn ará ilẹ̀ Juda, ati ìdajì àwọn ọmọ Israẹli ti sin ọba kọjá odò, ọba lọ sí Giligali, Kimhamu sì bá a lọ. +Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì bi í pé, “Kabiyesi, kí ló dé tí àwọn eniyan Juda, àwọn arakunrin wa, fi lérò pé àwọn ní ẹ̀tọ́ láti mú ọ lọ, ati láti sin ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn eniyan rẹ kọjá odò Jọdani?” +Àwọn eniyan Juda bá dáhùn pé, “Ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, ọ̀kan náà ni àwa ati ọba. Kí ló dé tí èyí fi níláti bà yín ninu jẹ́? Kì í ṣá ṣe pé òun ni ó ń bọ́ wa, a kò sì gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ̀.” +Àwọn ọmọ Israẹli dáhùn pé, “Ìlọ́po mẹ́wàá ẹ̀tọ́ tí ẹ ní sí ọba ni àwa ní, kì báà tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan náà ni yín. Kí ló dé tí ẹ fi fi ojú tẹmbẹlu wa? Ẹ má gbàgbé pé àwa ni a dábàá ati mú ọba pada sílé.”Ṣugbọn ọ̀rọ̀ àwọn ará ilẹ̀ Juda le ju ti àwọn ará ilẹ̀ Israẹli lọ. +Joabu bá wọlé tọ ọba lọ, ó wí fún un pé, “O ti dójúti àwọn ọmọ ogun rẹ lónìí, àwọn tí wọ́n gba ẹ̀mí rẹ là, ati ẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ, ati ti àwọn aya rẹ, ati àwọn obinrin rẹ; +nítorí pé o fẹ́ràn àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ, o sì kórìíra àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. O ti fihàn gbangba pé, àwọn ọ̀gágun ati ọmọ ogun rẹ kò jẹ́ nǹkankan lójú rẹ. Mo ti rí i gbangba lónìí pé, ìbá dùn mọ́ ọ ninu, bí gbogbo wa tilẹ̀ kú, tí Absalomu sì wà láàyè. +Yára dìde, kí o lọ tu àwọn ọmọ ogun ninu; nítorí pé mo fi OLUWA búra pé, bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní ku ẹnìkan ninu wọn pẹlu rẹ ní òwúrọ̀ ọ̀la. Èyí yóo wá burú ju gbogbo ibi tí ó ti bá ọ láti ìgbà èwe rẹ títí di òní lọ.” +Ọba bá dìde, ó lọ jókòó lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà ibodè. Àwọn eniyan rẹ̀ gbọ́ pé ó wà níbẹ̀, gbogbo wọn bá wá rọ̀gbà yí i ká.Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli ti sá, olukuluku ti pada sí ilé rẹ̀. +Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli káàkiri. Wọ́n ń wí láàrin ara wọn pé, “Ọba Dafidi ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, òun ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia, ṣugbọn nisinsinyii, ó ti sá kúrò nílùú fún Absalomu. +Joabu Bínú sí Dafidi. +Lẹ́yìn èyí, Dafidi bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, ṣé kí ń lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú Juda?”OLUWA sì dá a lóhùn pé, “Lọ.”Dafidi bá tún bèèrè pé, “Ìlú wo ni kí n lọ?”OLUWA ní, “Lọ sí ìlú Heburoni.” +Ẹni ogoji ọdún ni nígbà tí wọ́n fi jọba lórí Israẹli, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji.Ṣugbọn ẹ̀yìn Dafidi ni gbogbo ẹ̀yà Juda wà. +Ọdún meje ààbọ̀ ni Dafidi fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní ìlú Heburoni. +Abineri ọmọ Neri ati àwọn iranṣẹ Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ṣígun láti Mahanaimu, lọ sí ìlú Gibeoni. +Joabu, tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Seruaya, ati àwọn iranṣẹ Dafidi yòókù lọ pàdé wọn níbi adágún Gibeoni. Àwọn tí wọ́n tẹ̀lé Joabu jókòó sí ẹ̀gbẹ́ kan adágún náà, àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Abineri náà sì jókòó sí òdìkejì. +Abineri bá sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí àwọn bíi mélòó kan ninu àwọn ọmọkunrin láti ẹ̀gbẹ́ kinni keji bọ́ siwaju, kí wọ́n fi ohun ìjà dánrawò níwájú wa.”Joabu sì gbà bẹ́ẹ̀. +Àwọn mejila bá jáde láti ẹ̀gbẹ́ kinni keji; àwọn mejila ẹ̀gbẹ́ kan dúró fún ẹ̀yà Bẹnjamini ati Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu, wọ́n sì bá àwọn iranṣẹ Dafidi mejila, tí wọ́n jáde láti inú ẹ̀yà Juda jà. +Ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ẹ̀gbẹ́ kinni, dojú kọ ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ẹ̀gbẹ́ keji, wọ́n sì gbá ara wọn lórí mú. Ẹnìkínní ti idà rẹ̀ bọ ẹnìkejì rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́, àwọn mẹrẹẹrinlelogun ṣubú lulẹ̀, wọ́n sì kú. Ìdí nìyí tí wọ́n fi sọ ibẹ̀ ní Helikati-hasurimu. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni “Pápá Idà”; ó wà ní Gibeoni. +Ogun gbígbóná bẹ́ sílẹ̀ ní ọjọ́ náà, ṣugbọn àwọn eniyan Dafidi ṣẹgun Abineri ati àwọn eniyan Israẹli. +Àwọn ọmọ Seruaya mẹtẹẹta, Joabu, Abiṣai, ati Asaheli, wà lójú ogun náà. Ẹsẹ̀ Asaheli yá nílẹ̀ pupọ, àfi bí ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín. +Asaheli bẹ̀rẹ̀ sí lé Abineri lọ, bí ó sì ti ń lé e lọ, kò wo ọ̀tún, bẹ́ẹ̀ ni kò wo òsì. +Dafidi bá mú àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji; Ahinoamu ará Jesireeli, ati Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli lọ́wọ́ lọ. +Abineri bá bojúwo ẹ̀yìn, ó bèèrè pé, “Asaheli, ṣé ìwọ ni ò ń lé mi?”Asaheli sì dá a lóhùn pé, “Èmi ni.” +Abineri wí fún un pé, “Yà sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí o mú ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin, kí o sì kó gbogbo ìkógun rẹ̀.” Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò yipada kúrò lẹ́yìn rẹ̀. +Abineri tún pe Asaheli, ó tún sọ fún un pé, “Pada lẹ́yìn mi, má jẹ́ kí n pa ọ́? Ojú wo ni o sì fẹ́ kí n fi wo Joabu ẹ̀gbọ́n rẹ?” +Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò pada. Abineri bá sọ ọ̀kọ̀ ní àsọsẹ́yìn, ọ̀kọ̀ sì lọ bá Asaheli ní ikùn, ọ̀kọ̀ náà sì yọ jáde lẹ́yìn rẹ̀. Asaheli wó lulẹ̀, ó sì kú síbi tí ó ṣubú sí. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti dé ibi tí Asaheli kú sí, ni wọ́n ń dúró. +Ṣugbọn Joabu ati Abiṣai ń lé Abineri lọ, bí oòrùn ti ń lọ wọ̀, wọ́n dé ara òkè Ama tí ó wà níwájú Gia ní ọ̀nà aṣálẹ̀ Gibeoni. +Àwọn ọmọ ogun yòókù láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini kó ara wọn jọ sẹ́yìn Abineri, wọ́n sì dúró káàkiri lórí òkè, pẹlu ìmúra ogun. +Lẹ́yìn náà Abineri pe Joabu, ó ní, “Ṣé títí lae ni a óo máa ja ìjà yìí lọ ni? Àbí ìwọ náà kò rí i pé, bí a bá ja ogun yìí títí a fi pa ara wa tán, kò sí nǹkankan tí ẹnikẹ́ni yóo rí gbà, àfi ọ̀tá! Nígbà wo ni o fẹ́ dúró dà, kí o tó dá àwọn eniyan rẹ lẹ́kun pé kí wọ́n yé lépa àwọn arakunrin wọn?” +Joabu bá dáhùn pé, “Ọlọrun mọ̀, bí o bá dákẹ́ tí o kò sọ̀rọ̀ ni, àwọn eniyan mi kì bá máa le yín lọ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.” +Joabu bá fọn fèrè ogun, láti fi pe àwọn eniyan rẹ̀ pada. Nígbà náà ni wọ́n tó pada lẹ́yìn àwọn eniyan Israẹli, tí wọ́n sì dáwọ́ ogun dúró. +Gbogbo òru ọjọ́ náà ni Abineri ati àwọn eniyan rẹ̀ fi ń rìn pada lọ ní àfonífojì Jọdani, wọ́n kọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Gbogbo òwúrọ̀ ọjọ́ keji ni wọ́n sì fi rìn kí wọ́n tó pada dé Mahanaimu. +Ó kó àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ pẹlu, ati gbogbo ìdílé wọn, wọ́n sì ń gbé àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè Heburoni. +Nígbà tí Joabu pada lẹ́yìn Abineri, tí ó sì kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ jọ, ó rí i pé, lẹ́yìn Asaheli, àwọn mejidinlogun ni wọn kò rí mọ́. +Ṣugbọn àwọn eniyan Dafidi ti pa ọtalelọọdunrun (360) ninu àwọn eniyan Abineri. +Joabu ati àwọn eniyan rẹ̀ bá gbé òkú Asaheli, wọ́n sì lọ sin ín sí ibojì ìdílé wọn ní Bẹtilẹhẹmu. Gbogbo òru ọjọ́ náà ni wọ́n fi rìn; ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ni wọ́n pada dé Heburoni. +Lẹ́yìn náà, àwọn ará Juda wá sí Heburoni, wọ́n fi òróró yan Dafidi ní ọba wọn. Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé àwọn ará Jabeṣi Gileadi ni wọ́n sin òkú Saulu, +ó ranṣẹ sí wọn pé, “Kí OLUWA bukun yín nítorí pé ẹ ṣe olóòótọ́ sí Saulu ọba wa, ẹ sì sin òkú rẹ̀. +Kí OLUWA fi ìfẹ́ ńlá ati òdodo rẹ̀ hàn fun yín. Èmi náà yóo ṣe yín dáradára, nítorí ohun tí ẹ ṣe yìí. +Nítorí náà, ẹ mọ́kàn gírí kí ẹ sì ṣe akin; nítorí pé Saulu, oluwa yín ti kú, àwọn eniyan Juda sì ti fi òróró yàn mí gẹ́gẹ́ bí ọba wọn.” +Abineri ọmọ Neri, tíí ṣe balogun àwọn ọmọ ogun Saulu, gbé Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu s�� lọ sí Mahanaimu ní òdìkejì odò Jọdani. +Níbẹ̀ ni ó ti fi Iṣiboṣẹti jọba lórí gbogbo agbègbè Gileadi, Aṣuri, Jesireeli, Efuraimu, Bẹnjamini, ati lórí gbogbo ilẹ̀ Israẹli. +Wọ́n fi Dafidi Jọba Juda. +Aláìníláárí ẹ̀dá kan wà ní ààrin àwọn ará Giligali tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ọkunrin yìí fọn fèrè, ó ní,“Kò sí ohun tí ó kàn wá pẹlu Dafidi,a kò sì ní ìpín nílé ọmọ Jese.Ẹ pada sí ilé yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.” +Amasa kò fura rárá pé idà wà ní ọwọ́ Joabu. Joabu bá gún un ní idà níkùn, gbogbo ìfun rẹ̀ tú jáde. Amasa kú lẹsẹkẹsẹ, láì jẹ́ pé Joabu tún gún un ní idà lẹẹkeji.Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ bá ń lépa Ṣeba lọ. +Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Joabu dúró ti òkú Amasa, ó sì ń kígbe pé, “Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ti Joabu ati ti Dafidi tẹ̀lé Joabu.” +Òkú Amasa, tí ẹ̀jẹ̀ ti bò, wà ní ojú ọ̀nà gbangba, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kọjá, tí ó bá rí i ń dúró. Nígbà tí ọkunrin tí ó dúró ti òkú náà rí i pé gbogbo eniyan ní ń dúró, ó wọ́ òkú náà kúrò lójú ọ̀nà, sinu igbó, ó sì fi aṣọ bò ó. +Nígbà tí ó wọ́ ọ kúrò lójú ọ̀nà tán, gbogbo àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí sá tẹ̀lé Joabu, wọ́n ń lépa Ṣeba lọ. +Ṣeba la ilẹ̀ gbogbo ẹ̀yà Israẹli já, ó lọ sí ìlú Abeli ti Beti Maaka. Gbogbo àwọn ará Bikiri bá péjọ, wọ́n sì tẹ̀lé e wọnú ìlú náà. +Àwọn ọmọ ogun Joabu bá lọ dó ti ìlú náà, wọ́n fi erùpẹ̀ mọ òkítì gíga sára odi rẹ̀ lóde, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́ odi náà lábẹ́, wọ́n fẹ́ wó o lulẹ̀. +Obinrin ọlọ́gbọ́n kan wà ninu ìlú náà, tí ó kígbe láti orí odi, ó ní, “Ẹ tẹ́tí, ẹ gbọ́! Ẹ sọ fún Joabu kí ó wá gbọ́! Mo ní ọ̀rọ̀ kan tí mo fẹ́ bá a sọ.” +Joabu bá lọ sibẹ. Obinrin náà bèèrè pé, “Ṣé ìwọ ni Joabu?”Joabu dáhùn pé, “Èmi ni.”Obinrin náà ní, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí èmi, iranṣẹbinrin rẹ fẹ́ sọ.”Joabu dá a lóhùn pé, “Mò ń gbọ́.” +Obinrin yìí ní, “Nígbà àtijọ́, wọn a máa wí pé, ‘Bí ọ̀rọ̀ kan bá ta kókó, ìlú Abeli ni wọ́n ti í rí ìtumọ̀ rẹ̀.’ Lóòótọ́ sì ni, ibẹ̀ gan-an ni wọ́n tií rí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀. +Abeli jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí ó fẹ́ alaafia, tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ jùlọ ní Israẹli. Ṣé o wá fẹ́ pa ìlú tí ó jẹ́ ìyá ní Israẹli run ni? Kí ló dé tí o fi fẹ́ pa nǹkan OLUWA run?” +Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lẹ́yìn Dafidi, wọ́n tẹ̀lé Ṣeba. Ṣugbọn àwọn eniyan Juda tẹ̀lé Dafidi, ọba wọn, pẹlu ẹ̀mí òtítọ́, láti odò Jọdani títí dé Jerusalẹmu. +Joabu dáhùn pé, “Rárá o! Kò sí ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe ìlú yìí ni mo fẹ́ parun. +Ọkunrin kan, tí ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti agbègbè olókè ti Efuraimu, ni ó ń dìtẹ̀ mọ́ Dafidi ọba. Bí o bá ti fa òun nìkan ṣoṣo kalẹ̀, n óo kúrò ní ìlú yín.”Obinrin yìí bá dáhùn pé, “A óo ju orí rẹ̀ sílẹ̀ sí ọ, láti orí odi.” +Obinrin yìí bá tọ gbogbo àwọn ará ìlú lọ, ó sì fi ọgbọ́n bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n bá gé orí Ṣeba, wọ́n jù ú sí Joabu láti orí odi. Joabu bá fọn fèrè ogun, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì fi ìlú náà sílẹ̀, wọ́n pada sí ilé. Joabu bá pada lọ sọ́dọ̀ ọba, ní Jerusalẹmu. +Joabu ni balogun àwọn ọmọ ogun ní Israẹli. Bẹnaya ọmọ Jehoiada sì ní olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba. +Adoramu ni olórí àwọn tí wọ́n ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́. Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn àkọsílẹ̀ ní ààfin ọba. +Ṣefa ni akọ̀wé gbọ̀ngàn ìdájọ́ rẹ̀. Sadoku ati Abiatari ni alufaa. +Ira, ará ìlú Jairi náà jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn alufaa Dafidi. +Nígbà tí Dafidi pada dé ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu, ó mú àwọn obinrin rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó fi sílẹ̀, pé kí wọ́n máa tọ́jú ààfin, ó fi wọ́n sinu ilé kan pẹlu olùṣọ́, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún wọn, ṣugbọn kò bá wọn lòpọ̀ mọ́. Ninu ìhámọ́ ni wọ́n wà, tí wọ́n ń gbé bí opó, títí tí wọ́n fi kú. +Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Amasa pé, “Pe gbogbo àwọn ọkunrin Juda jọ, kí o sì kó wọn wá sọ́dọ̀ mi láàrin ọjọ́ mẹta; kí ìwọ náà sì wá.” +Amasa bá lọ kó àwọn eniyan Juda jọ, ṣugbọn kò dé títí àkókò tí ọba dá fún un fi kọjá. +Ọba bá pe Abiṣai, ó ní, “Ìyọnu tí Ṣeba yóo kó bá wa yóo ju ti Absalomu lọ. Nítorí náà, kó àwọn eniyan mi lẹ́yìn kí o sì máa lépa rẹ̀ lọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè gba àwọn ìlú olódi bíi mélòó kan kí ó sì dá wahala sílẹ̀ fún wa.” +Gbogbo àwọn ọmọ ogun Joabu, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun yòókù, tí wọ́n kù ní Jerusalẹmu bá tẹ̀lé Abiṣai láti lépa Ṣeba. +Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá kan, tí ó wà ní Gibeoni, Amasa lọ pàdé wọn. Ẹ̀wù ọmọ ogun ni Joabu wọ̀; ó sán ìgbànú kan, idà rẹ̀ sì wà ninu àkọ̀ lára ìgbànú tí ó ti sán mọ́ ìbàdí. Bí Joabu ti rìn siwaju bẹ́ẹ̀ ni idà yìí bọ́ sílẹ̀. +Ó bá bèèrè lọ́wọ́ Amasa pé, “Ṣé alaafia ni, arakunrin mi?” Ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbá Amasa ní irùngbọ̀n mú, bí ẹni pé ó fẹ́ fi ẹnu kò ó ní ẹnu. +Ọ̀tẹ̀ Ṣeba. +Ní àkókò ìjọba Dafidi, ìyàn ńlá kan mú, fún odidi ọdún mẹta. Dafidi bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà lọ́dọ̀ OLUWA. OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu ati ìdílé rẹ̀ jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.” +Risipa, ọmọbinrin Aya, fi aṣọ ọ̀fọ̀ pa àtíbàbà fún ara rẹ̀ lórí òkúta, níbi tí òkú àwọn tí wọ́n pa wà. Ó wà níbẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí di àkókò tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ní ojúmọmọ, kò jẹ́ kí àwọn ẹyẹ jẹ wọ́n ní ọ̀sán, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú fọwọ́ kàn wọ́n lóru. +Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí Risipa, ọmọ Aya, obinrin Saulu ṣe, +ó lọ kó egungun Saulu, ati ti Jonatani, ọmọ rẹ̀, tí ó wà lọ́dọ̀ àwọn ará Jabeṣi-Gileadi. (Àwọn ará Jabeṣi ti jí àwọn egungun náà kó kúrò ní ìta gbangba, ní ààrin ìlú ní Beti Ṣani, níbi tí àwọn ará Filistia so wọ́n kọ́ sí, ní ọjọ́ tí wọ́n pa wọ́n ní òkè Giliboa.) +Láti ibẹ̀ ni ó ti kó egungun Saulu, ati ti Jonatani, ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì kó egungun àwọn mejeeje tí wọ́n so kọ́ pẹlu. +Wọ́n sin egungun Saulu, ati ti Jonatani, sinu ibojì Kiṣi, baba rẹ̀, ní Sela ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini. Gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ ni wọ́n ṣe. Lẹ́yìn náà, ni Ọlọrun gbọ́ adura tí wọ́n ń gbà fún ilẹ̀ náà. +Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì lọ bá àwọn ará Filistia jagun. Bí wọ́n ti ń jà, àárẹ̀ mú Dafidi. +Òmìrán kan tí ń jẹ́ Iṣibibenobu, gbèrò láti pa Dafidi. Ọ̀kọ̀ Iṣibibenobu yìí wọ̀n tó ọọdunrun ṣekeli idẹ, ó sì so idà tuntun mọ́ ẹ̀gbẹ́. +Ṣugbọn Abiṣai, ọmọ Seruaya, sáré wá láti ran Dafidi lọ́wọ́, ó kọlu òmìrán náà, ó sì pa á. Láti ìgbà náà ni àwọn ọmọ ogun Dafidi ti búra fún un pé, “A kò ní jẹ́ kí o bá wa lọ sí ojú ogun mọ́ kí á má baà pàdánù rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìrètí Israẹli.” +Lẹ́yìn èyí, ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia, ní Gobu, ninu ogun yìí ni Sibekai ará Huṣa ti pa Safu, ọ̀kan ninu àwọn ìran òmìrán. +Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia kan náà, ní Gobu. Ninu ogun yìí ni Elihanani ọmọ Jaareoregimu, ará Bẹtilẹhẹmu, ti pa Goliati, ará Giti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ nípọn tó igi òfì tí àwọn obinrin fi máa ń hun aṣọ. +Àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli. Ara àwọn ará Amori tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti ṣèlérí pé àwọn kò ní pa wọ́n, sibẹsibẹ Saulu gbìyànjú láti pa wọ́n run, nítorí ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli ati Juda. +Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ ní Gati. Òmìrán kan wà níbẹ̀ tí ó fẹ́ràn ogun jíjà pupọ, ìka mẹfa mẹfa ni ó ní ní ọwọ́ kọ̀ọ̀kan, ati ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan; ìka ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ mẹrinlelogun. +Jonatani, ọmọ Ṣimei, arakunrin Dafidi pa á, nígbà tí ó ń fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe yẹ̀yẹ́. +Láti ìran àwọn òmìrán ìlú Gati ni àwọn mẹrẹẹrin ti wá, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni ó sì pa wọ́n. +Dafidi bá pe àwọn ará Gibeoni, ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín? Ọ̀nà wo ni mo lè gbà ṣe àtúnṣe ibi tí wọ́n ṣe si yín, kí ẹ baà lè súre fún àwọn eniyan OLUWA?” +Wọ́n dá a lóhùn pé, “Aáwọ̀ tí ó wà láàrin àwa ati Saulu ati ìdílé rẹ̀, kì í ṣe ohun tí a lè fi wúrà ati fadaka parí, a kò sì fẹ́ pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli.”Dafidi bá tún bèèrè pé, “Kí ni ẹ wá fẹ́ kí n ṣe fun yín?” +Wọ́n dáhùn pé, “Saulu fẹ́ pa wá run, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ninu wa wà láàyè níbikíbi, ní ilẹ̀ Israẹli. +Nítorí náà, fún wa ní meje ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, kí á lè so wọ́n kọ́ níwájú OLUWA ní Gibea, ní orí òkè OLUWA.”Dafidi dáhùn pé, “N óo kó wọn lé yín lọ́wọ́.” +Ṣugbọn nítorí majẹmu tí ó wà láàrin Dafidi ati Jonatani, Dafidi kò fi ọwọ́ kan Mẹfiboṣẹti, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu. +Ṣugbọn ó mú Arimoni ati Mẹfiboṣẹti àwọn ọmọkunrin mejeeji tí Risipa, ọmọ Aya, bí fún Saulu; ó sì tún mú àwọn ọmọ marun-un tí Merabu, ọmọbinrin Saulu, bí fún Adirieli ọmọ Basilai ará Mehola. +Dafidi kó wọn lé àwọn ará Gibeoni lọ́wọ́, àwọn ará Gibeoni sì so wọ́n kọ́ sórí igi, lórí òkè níwájú OLUWA, àwọn mejeeje sì kú papọ̀. Àkókò tí wọ́n kú yìí jẹ́ àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà baali nígbà tí àkókò ìrúwé fẹ́rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀. +Wọ́n Pa Àwọn Ọmọ Ọmọ Saulu. +Nígbà tí OLUWA gba Dafidi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ati lọ́wọ́ Saulu, Dafidi kọ orin yìí sí OLUWA pé: +Ó tẹ àwọn ọ̀run ba, ó sì sọ̀kalẹ̀;ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. +Ó gun orí Kerubu, ó fò,afẹ́fẹ́ ni ó fi ṣe ìyẹ́ tí ó fi ń fò. +Ó fi òkùnkùn bo ara,ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn,tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí. +Ẹ̀yinná tí ń jó ń jáde,láti inú ìmọ́lẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. +“OLUWA sán ààrá láti ọ̀run wá,ayé sì gbọ́ ohùn ọ̀gá ògo. +Ó ta ọpọlọpọ ọfà, ó sì tú wọn ká.Ó tan mànàmáná, wọ́n sì ń sá. +Ìsàlẹ̀ òkun di gbangba, ìpìlẹ̀ ayé sì ṣí sílẹ̀,nígbà tí OLUWA bá wọn wí,tí ó sì fi ibinu jágbe mọ́ wọn. +“OLUWA nawọ́ sílẹ̀ láti òkè wá, ó dì mí mú,ó fà mí jáde kúrò ninu omi jíjìn. +Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi, tí ó lágbára;ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi;nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ. +Nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú; wọ́n gbógun tì mí,ṣugbọn OLUWA dáàbò bò mí. +“OLUWA ni àpáta mi,ààbò mi, ati olùgbàlà mi; +Ó ràn mí lọ́wọ́,ó kó mi yọ ninu ewu,ó sì gbà mí là,nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi. +“OLUWA fún mi ní èrè òdodo mi,ó san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo jẹ́ aláìlẹ́bi. +Nítorí pé mo pa àwọn òfin OLUWA mọ́,n kò sì ṣe agídí, kí n yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi. +Mo ti tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀,n kò sì ṣe àìgbọràn sí àwọn ìlànà rẹ̀. +N kò lẹ́bi níwájú rẹ̀,mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá. +Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,ati gẹ́gẹ́ bí mo ti jẹ́ mímọ́ níwájú rẹ̀. +“OLUWA, ò máa ṣe olóòótọ́ sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá hu ìwà òtítọ́ sí ọ;ò sì máa fi ara rẹ hàn bí aláìlẹ́bi, fún gbogbo àwọn tí kò ní ẹ̀bi. +Ọlọrun, mímọ́ ni ọ́, sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá mọ́,ṣugbọn o kórìíra gbogbo àwọn eniyan burúkú. +Ò máa gba àwọn onírẹ̀lẹ̀,o dójú lé àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀. +“OLUWA, ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi,ìwọ ni o sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀. +Ọlọrun mi, àpáta mi,ọ̀dọ̀ ẹni tí mo sá pamọ́ sí.Àpáta mi ati ìgbàlà mi,ààbò mi ati ibi ìpamọ́ mi,olùgbàlà mi, ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá. +Nípa agbára rẹ, mo lè ṣẹgun àwọn ọ̀tá mi,mo sì lè fo odi kọjá. +Ní ti Ọlọrun yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀,òtítọ́ ni ìlérí OLUWA,ó sì jẹ́ apata fun gbogbo àwọn tí wọ́n bá sápamọ́ sábẹ́ ààbò rẹ̀. +Ta ni Ọlọrun bí kò ṣe OLUWA?Ta sì ni àpáta ààbò bí kò ṣe Ọlọrun wa? +Ọlọrun yìí ni ààbò mi tí ó lágbára,ó mú gbogbo ewu kúrò ní ọ̀nà mi. +Ó fún ẹsẹ̀ mi lókun láti sáré bí àgbọ̀nrín,ó sì mú kí n wà ní àìléwu lórí àwọn òkè. +Ó kọ́ mi ní ogun jíjà,tóbẹ́ẹ̀ tí mo lè lo ọrun idẹ. +“O fún mi ní àpáta ìgbàlà rẹ,ìrànlọ́wọ́ rẹ ni ó sọ mí di ẹni ńlá. +Ìwọ ni o kò jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tá tẹ̀ mí,bẹ́ẹ̀ ni o kò jẹ́ kí ẹsẹ̀ mí kí ó yẹ̀. +Mo lépa àwọn ọ̀tá mi,mo sì ṣẹgun wọnn kò pada lẹ́yìn wọn títí tí mo fi pa wọ́n run. +Mo pa wọ́n run, mo bì wọ́n lulẹ̀;wọn kò sì lè dìde mọ́;wọ́n ṣubú lábẹ́ ẹsẹ̀ mi. +Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ,Ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. +Ìwọ ni o fún mi lágbára láti jagun,o jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi rì lábẹ́ mi. +O mú kí àwọn ọ̀tá mi sá fún mi,mo sì pa àwọn tí wọ́n kórìíra mi run. +Wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ káàkiri,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n;wọ́n pe OLUWA,ṣugbọn kò dá wọn lóhùn. +Mo fọ́ wọn túútúú, wọ́n sì dàbí erùpẹ̀ ilẹ̀;mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì dàbí ẹrọ̀fọ̀ lójú títì. +“Ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìjà àwọn eniyan mi,o sì mú kí ìjọba mi dúró lórí àwọn orílẹ̀ èdè;àwọn eniyan tí n kò mọ̀ rí di ẹni tí ó ń sìn mí. +Àwọn àjèjì ń wólẹ̀ níwájú mi,ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bá ti gbúròó mi, ni wọ́n ń mú àṣẹ mi ṣẹ. +Ẹ̀rù ba àwọn àjèjì,wọ́n gbọ̀n jìnnìjìnnì jáde ní ibi ààbò wọn. +“OLUWA wà láàyè,ìyìn ni fún àpáta ààbò mi.Ẹ gbé Ọlọrun mi ga,ẹni tíí ṣe àpáta ìgbàlà mi. +Ọlọrun ti jẹ́ kí n gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi,ó ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba lábẹ́ mi; +ó sì fà mí yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.“OLUWA, ìwọ ni o gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá mi lọ,o sì dáàbò bò mí, lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá. +“Ikú yí mi káàkiri, bí ìgbì omi;ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi ríru omi; +Nítorí náà, n óo máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,n óo máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ. +Ọlọrun fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀,ó sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ han ẹni tí ó fi àmì òróró yàn,àní Dafidi ati arọmọdọmọ rẹ̀ laelae!” +isà òkú ya ẹnu sílẹ̀ dè mí,ewu ikú sì dojú kọ mí. +Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWAmo ké pe Ọlọrun mi,ó gbọ́ ohùn mi láti inú tẹmpili rẹ̀;ó sì tẹ́tí sí igbe mi. +“Ayé mì, ó sì wárìrì;ìpìlẹ̀ àwọn ọ̀run sì wárìrì,ó mì tìtì, nítorí ibinu Ọlọrun. +Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀,iná ajónirun sì jáde láti ẹnu rẹ̀;ẹ̀yinná tí ó pọ́n rẹ̀rẹ̀ ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ jáde. +Orin Ìṣẹ́gun Tí Dafidi Kọ. +Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi nìyí; àní, ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Dafidi, ọmọ Jese, tí a gbé ga ní Israẹli, ẹni àmì òróró Ọlọrun Jakọbu, olórin dídùn ní Israẹli: +Ṣugbọn Eleasari dúró gbọningbọnin, ó sì bá àwọn ará Filistia jà títí tí ọwọ́ rẹ̀ fi wo koko mọ́ idà rẹ̀, tí kò sì le jù ú sílẹ̀ mọ́. OLUWA ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà. Lẹ́yìn tí ogun náà parí ni àwọn ọmọ ogun Israẹli tó pada sí ibi tí Eleasari wà, tí wọ́n lọ kó àwọn ohun ìjà tí ó wà lára àwọn tí ogun pa. +Ẹnìkẹta ninu àwọn akọni náà ni Ṣama, ọmọ Agee, ará Harari. Ní àkókò kan, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ sí Lehi, níbi tí oko ewébẹ̀ kan wà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sá fún àwọn ará Filistia, +ṣugbọn Ṣama dúró gbọningbọnin ní ojú ogun. Ó jà kíkankíkan, ó sì pa àwọn ará Filistia. OLUWA sì ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà. +Nígbà tí àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè súnmọ́ tòsí, mẹta ninu àwọn ọgbọ̀n akọni náà lọ sí inú ihò àpáta tí ó wà ní Adulamu, níbi tí Dafidi wà nígbà náà, nígbà tí ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini pàgọ́ wọn sí àfonífojì Refaimu. +Dafidi wà ní orí òkè kan tí wọ́n mọ odi yípo, ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini kan ti gba Bẹtilẹhẹmu, wọ́n sì wà níbẹ̀. +Ọkàn ilé fa Dafidi pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “Báwo ni ìbá ti dùn tó, kí ẹnìkan bu omi wá fún mi mu, láti inú kànga tí ó wà ní ẹnubodè Bẹtilẹhẹmu.” +Àwọn akọni ọmọ ogun mẹta yìí bá fi tipátipá la àgọ́ àwọn ará Filistia kọjá, wọ́n pọn omi láti inú kànga náà, wọ́n sì gbé e wá fún Dafidi. Ṣugbọn Dafidi kọ̀, kò mu ún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dà á sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun mímú fún OLUWA. +Ó sì wí pé, “OLUWA, kò yẹ kí n mu omi yìí, nítorí pé, yóo dàbí ẹni pé ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkunrin mẹta yìí, tí wọ́n fi orí la ikú lọ ni mò ń mu.” Nítorí náà, ó kọ̀, kò mu ún.Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ara àwọn nǹkan ìgboyà tí àwọn akọni ọmọ ogun mẹta náà ṣe. +Arakunrin Joabu, tí ń jẹ́ Abiṣai, ọmọ Seruaya ni aṣiwaju fún “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni Olókìkí.” Ó fi idà rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀, ó di olókìkí láàrin wọn. +Òun ni ó jẹ́ olókìkí jùlọ ninu “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni,” ó sì di aṣiwaju wọn, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” àkọ́kọ́. +“Ẹ̀mí OLUWA ń gba ẹnu mi sọ̀rọ̀,ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà ní ẹnu mi. +Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ará Kabiseeli, náà tún jẹ́ akọni ọmọ ogun, ọpọlọpọ nǹkan ńláńlá ni ó fi ìgboyà ṣe. Ó pa àwọn akikanju ọmọ ogun ará Moabu meji ní àkókò kan. Ní ọjọ́ kan lẹ́yìn tí yìnyín bọ́ sílẹ̀, ó wọ inú ihò kan lọ, ó sì pa kinniun kan sibẹ. +Bẹ́ẹ̀ náà ni, ó pa ọkunrin ará Ijipti kan tí ó ṣígbọnlẹ̀, tí ó sì dira ogun tòun tọ̀kọ̀. Kùmọ̀ lásán ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ tí ó fi dojú kọ ọ́, ó já ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọmọ ogun ará Ijipti yìí gbà, ó sì fi pa á. +Àwọn nǹkan akikanju ti Bẹnaya ṣe nìwọ̀nyí, ó sì ní òkìkí, yàtọ̀ sí ti “Àwọn Akọni Mẹta”. +Akọni ni láàrin “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni”, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” ti àkọ́kọ́, òun ni Dafidi sì fi ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀. +Àwọn mìíràn tí wọ́n tún jẹ́ ara “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni” náà nìwọ̀ny��: Asaheli arakunrin Joabu, ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu. +Ṣama ati Elika, àwọn mejeeji jẹ́ ará Harodu; +Helesi, ará Paliti, Ira, ọmọ Ikeṣi, ará Tekoa; +Abieseri, ará Anatoti, ati Mebunai, ará Huṣa; +Salimoni, ará Ahohi, ati Maharai, ará Netofa; +Helebu, ọmọ Baana, tí òun náà jẹ́ ará Netofa, ati Itai, ọmọ Ribai, ará Gibea, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini; +Ọlọrun Israẹli ti sọ̀rọ̀,Àpáta Israẹli ti wí fún mi pé,‘Ẹni yòówù tí ó bá fi òtítọ́ jọba,tí ó ṣe àkóso pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun, +Bẹnaya ará Piratoni ati Hidai ará ẹ̀bá àwọn odò Gaaṣi; +Abialiboni ará Araba, ati Asimafeti ará Bahurimu; +Eliaba, ará Ṣaaliboni, àwọn ọmọ Jaṣeni, ati Jonatani; +Ṣama, ará Harari, Ahiamu, ọmọ Ṣarari, ará Harari; +Elifeleti, ọmọ Ahasibai, ará Maaka, Eliamu, ọmọ Ahitofẹli, ará Gilo; +Hesiro, ará Kamẹli, Paarai, ará Abiti; +Igali, ọmọ Natani, ará Soba, Bani, ará Gadi; +Seleki, ará Amoni, Naharai, ará Beeroti, tí ó máa ń ru ihamọra Joabu, ọmọ Seruaya. +Ira ati Garebu, àwọn mejeeji jẹ́ ará Itiri; +ati Uraya, ará Hiti.Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ akọni ọmọ ogun náà jẹ́ mẹtadinlogoji. +a máa tàn sí wọn bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,bí oòrùn tí ó ń ràn ní òwúrọ̀ kutukutu,ní ọjọ́ tí kò sí ìkùukùu;ó dàbí òjò tí ń mú kí koríko hù jáde láti inú ilẹ̀.’ +“Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún arọmọdọmọ mi níwájú Ọlọrun,nítorí pé, ó ti bá mi dá majẹmu ayérayé nípa ohun gbogbo,majẹmu tí kò lè yipada, ati ìlérí tí kò ní yẹ̀.Yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ fún mi.Yóo ràn mí lọ́wọ́, yóo fún mi ní ìfẹ́ ọkàn mi. +Ṣugbọn àwọn tí wọn kò mọ Ọlọrundàbí igi ẹ̀gún tí a gbé sọnù,kò sí ẹni tí ó lè fi ọwọ́ lásán gbá wọn mú. +Ẹni tí yóo fọwọ́ kan ẹ̀gún gbọdọ̀ lo ohun èlò tí a fi irin ṣe tabi igi ọ̀kọ̀,láti fi wọ́n jóná patapata.” +Orúkọ àwọn ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n jẹ́ akọni ati akikanju nìwọ̀nyí: Ekinni ni, Joṣebu-Baṣebeti, ará Takimoni, òun ni olórí ninu “Àwọn Akọni Mẹta,” ó fi ọ̀kọ̀ bá ẹgbẹrin (800) eniyan jà, ó sì pa gbogbo wọn ninu ogun kan ṣoṣo. +Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni, Eleasari, ọmọ Dodo, ti ìdílé Ahohi, ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí wọ́n pe àwọn ará Filistia níjà, tí wọ́n kó ara wọn jọ fún ogun, tí àwọn ọmọ ogun Israẹli sì sá sẹ́yìn. +Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Dafidi. +Inú tún bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ti Dafidi láti kó ìyọnu bá wọn. OLUWA wí fún un pé, lọ ka àwọn ọmọ Israẹli ati ti Juda. +Ṣugbọn lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ka àwọn eniyan náà tán, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dà á láàmú. Ó bá wí fún OLUWA pé, “Ohun tí mo ṣe yìí burú gan-an, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá gbáà ni. Jọ̀wọ́, dáríjì èmi iranṣẹ rẹ, ìwà òmùgọ̀ gbáà ni mo hù.” +Nígbà tí Dafidi jí ní òwúrọ̀, OLUWA rán wolii Gadi, aríran rẹ̀ sí i pé, +“Lọ sọ fún Dafidi pé mo fi nǹkan mẹta siwaju rẹ̀; kí ó yan ọ̀kan tí ó fẹ́ kí n ṣe sí òun ninu mẹtẹẹta.” +Gadi bá lọ sọ ohun tí OLUWA wí fún Dafidi. Ó bèèrè pé, “Èwo ni o fẹ́ yàn ninu mẹtẹẹta yìí, ekinni, kí ìyàn mú ní ilẹ̀ rẹ fún ọdún mẹta; ekeji, kí o máa sá fún àwọn ọ̀tá rẹ fún oṣù mẹta; ẹkẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn jà fún ọjọ́ mẹta ní gbogbo ilẹ̀ rẹ? Rò ó dáradára, kí o sì sọ èyí tí o fẹ́, kí n lọ sọ fún OLUWA.” +Dafidi dá Gadi lóhùn pé, “Ìdààmú ńlá ni ó dé bá mi yìí, ṣugbọn ó yá mi lára kí OLUWA jẹ wá níyà ju pé kí ó fi mí lé eniyan lọ́wọ́ lọ; nítorí pé, aláàánú ni OLUWA.” +Nítorí náà, OLUWA fi àjàkálẹ̀ àrùn bá Israẹli jà. Ó bẹ̀rẹ̀ láti òwúrọ̀ títí di àkókò tí ó yàn jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Láti Dani títí dé Beeriṣeba, gbogbo àwọn tí ó kú jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ati ẹgbaarun (70,000). +Nígbà tí angẹli OLUWA náà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti máa pa Jerusalẹmu run, OLUWA yí ọkàn pada nípa jíjẹ tí ó ń jẹ àwọn eniyan náà níyà. Ó bá wí fún angẹli náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Níbi ìpakà Arauna ará Jebusi kan ni angẹli náà wà nígbà náà. +Nígbà tí Dafidi rí angẹli tí ó ń pa àwọn eniyan náà, ó wí fún OLUWA pé, “Èmi ni mo ṣẹ̀, èmi ni mo ṣe burúkú. Kí ni àwọn eniyan wọnyi ṣe? Èmi ati ìdílé baba mi ni ó yẹ kí ó jẹ níyà.” +Ní ọjọ́ náà gan-an, Gadi tọ Dafidi lọ, ó sì wí fún un pé, “Lọ sí ibi ìpakà Arauna kí o sì tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA níbẹ̀.” +Dafidi pa àṣẹ OLUWA mọ́, ó sì lọ sí ibi ìpakà Arauna, gẹ́gẹ́ bí Gadi ti sọ fún un. +Dafidi bá pàṣẹ fún Joabu, ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ó ní, “Ẹ lọ sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli, láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí ẹ sì ka gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀, kí n lè mọ iye wọn.” +Nígbà tí Arauna wo ìsàlẹ̀, ó rí ọba ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọn ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó lọ pàdé rẹ̀, ó kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀. +Ó bi í pé, “Ṣé kò sí, tí oluwa mi, ọba, fi wá sọ́dọ̀ èmi, iranṣẹ rẹ̀?”Dafidi dá a lóhùn pé, “Ilẹ̀ ìpakà rẹ ni mo fẹ́ rà, mo fẹ́ tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí lè dáwọ́ dúró.” +Arauna dá a lóhùn pé, “Máa mú un, kí o sì mú ohunkohun tí o bá fẹ́ fi rúbọ sí OLUWA. Akọ mààlúù nìwọ̀nyí, tí o lè fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Àwọn àjàgà wọn nìwọ̀nyí, ati àwọn igi ìpakà tí o lè lò fún igi ìdáná.” +Arauna kó gbogbo rẹ̀ fún ọba, ó ní, “Kí OLUWA Ọlọrun rẹ gba ẹbọ náà.” +Ṣugbọn ọba dá a lóhùn pé, “Rárá o, n óo san owó rẹ̀ fún ọ, nítorí pé ohunkohun tí kò bá ní ná mi lówó, n kò ní fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun mi.” Dafidi bá ra ibi ìpakà ati àwọn akọ mààlúù náà, ní aadọta ṣekeli owó fadaka. +Ó kọ́ pẹpẹ kan sibẹ fún OLUWA, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. OLUWA gbọ́ adura rẹ̀ lórí ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀ àrùn náà sì dáwọ́ dúró ní ilẹ̀ Israẹli. +Ṣugbọn Joabu bi ọba léèrè pé, “Kí OLUWA Ọlọrun rẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ jù báyìí lọ, ní ìlọ́po ọ̀nà ọgọrun-un (100), nígbà tí oluwa mi ṣì wà láàyè; ṣugbọn, kí ló dé tí kabiyesi fi fẹ́ ka àwọn eniyan wọnyi?” +Ṣugbọn àṣẹ tí ọba pa ni ó borí. Ni Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ bá jáde kúrò níwájú ọba, wọ́n bá lọ ka àwọn ọmọ Israẹli. +Wọ́n ré odò Jọdani kọjá, wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù Aroeri, ìlú tí ó wà ní ààrin àfonífojì, ní agbègbè Gadi. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti lọ sí ìhà àríwá, títí dé Jaseri. +Wọ́n lọ sí Gileadi, ati sí Kadeṣi ní ilẹ̀ àwọn ará Hiti. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí Dani. Láti Dani, wọ́n lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé Sidoni. +Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí apá gúsù. Wọ́n dé ìlú olódi ti Tire, títí lọ dé gbogbo ìlú àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Kenaani. Níkẹyìn, wọ́n wá sí Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù Juda. +Oṣù mẹsan-an ati ogúnjọ́ ni ó gbà wọ́n láti lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Israẹli, lẹ́yìn náà, wọ́n pada sí Jerusalẹmu. +Joabu sọ iye àwọn eniyan tí ó kà fún ọba: Ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) ni àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun jà ní ilẹ̀ Israẹli, àwọn ti ilẹ̀ Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdọgbọn (500,000). +Dafidi Ka Àwọn Eniyan Israẹli. +Àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn ìdílé Saulu, ati àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn ìdílé Dafidi bá ara wọn jagun fún ìgbà pípẹ́. Bí agbára Dafidi ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni agbára àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Saulu ń dínkù. +pé, òun yóo gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ ìdílé Saulu, yóo sì fi Dafidi jọba lórí Juda jákèjádò, láti Dani títí dé Beeriṣeba.” +Iṣiboṣẹti kò sì lè dá Abineri lóhùn nítorí ó bẹ̀rù rẹ̀. +Abineri bá ranṣẹ sí Dafidi ní Heburoni pé, “Ṣebí ìwọ ni o ni ilẹ̀ yìí? Bá mi dá majẹmu, n óo wà lẹ́yìn rẹ, n óo sì mú kí gbogbo Israẹli pada sọ́dọ̀ rẹ.” +Dafidi bá dáhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọ dá majẹmu. Ṣugbọn nǹkankan ni mo fẹ́ kí o ṣe, o kò ní fi ojú kàn mí, àfi bí o bá mú Mikali ọmọbinrin Saulu lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń bọ̀ wá rí mi.” +Dafidi bá rán àwọn oníṣẹ́ kan sí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, pé kí ó dá Mikali, aya òun, tí òun san ọgọrun-un awọ orí adọ̀dọ́ àwọn ará Filistia lé lórí pada fún òun. +Iṣiboṣẹti bá ranṣẹ lọ gba Mikali lọ́wọ́ Palitieli, ọmọ Laiṣi, ọkọ rẹ̀. +Ṣugbọn bí ó ti ń lọ ni ọkọ rẹ̀ ń sọkún tẹ̀lé e títí tí ó fi dé Bahurimu, ibẹ̀ ni Abineri ti dá a pada, ó sì pada. +Abineri tọ àwọn àgbààgbà Israẹli lọ, ó ní, “Ó pẹ́ tí ẹ ti fẹ́ kí Dafidi jẹ́ ọba yín. +Àkókò nìyí láti ṣe ohun tí ẹ ti fẹ́ ṣe, nítorí pé OLUWA ti ṣe ìlérí fún Dafidi pé Dafidi ni òun óo lò láti gba àwọn ọmọ Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistia ati gbogbo àwọn ọ̀tá wọn yòókù.” +Abineri bá àwọn ará Bẹnjamini sọ̀rọ̀ pẹlu. Lẹ́yìn náà ó lọ bá Dafidi ní Heburoni láti sọ ohun tí àwọn ará Bẹnjamini ati gbogbo ọmọ Israẹli ti gbà láti ṣe fún Dafidi. +Ọmọkunrin mẹfa ni wọ́n bí fún Dafidi nígbà tí ó wà ní Heburoni. Aminoni tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Ahinoamu, ará Jesireeli, ni àkọ́bí. +Nígbà tí Abineri dé ọ̀dọ̀ Dafidi ní Heburoni pẹlu ogún ọkunrin tí ń bá a lọ, Dafidi se àsè ńlá fún wọn. +Abineri bá sọ fún Dafidi pé, “N óo lọ, n óo wá ọ̀nà tí gbogbo Israẹli yóo fi wà lẹ́yìn rẹ, oluwa mi, (ọba), tí wọn yóo bá ọ dá majẹmu tí o óo sì jọba lórí gbogbo ibi tí ọkàn rẹ bá fẹ́.” Dafidi ní kí ó máa lọ, ó sì lọ ní alaafia. +Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, ni Joabu ati àwọn ọmọ ogun Dafidi pada dé láti ibi tí wọ́n ti lọ ja ogun kan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun bọ̀. Ṣugbọn Abineri kò sí lọ́dọ̀ Dafidi, ní Heburoni, nígbà tí wọ́n dé, nítorí pé Dafidi ti ní kí ó máa pada lọ, ó sì ti lọ ní alaafia. +Nígbà tí Joabu ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e dé, wọ́n sọ fún Joabu pé, “Abineri ti wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi ọba, ọba sì ti jẹ́ kí ó lọ ní alaafia.” +Joabu bá lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, ó bèèrè pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, Abineri wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, o sì jẹ́ kí ó lọ bẹ́ẹ̀? +Ṣebí o mọ̀ pé ó wá tàn ọ́ jẹ ni? Ó wá fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ibi tí ò ń lọ, ati gbogbo ohun tí ò ń ṣe ni.” +Nígbà tí Joabu kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó ranṣẹ lọ pe Abineri, wọ́n sì dá a pada láti ibi kànga Sira, ṣugbọn Dafidi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀. +Nígbà tí Abineri pada dé Heburoni, Joabu mú un lọ sí kọ̀rọ̀ kan, níbi ẹnubodè, bí ẹni pé ó fẹ́ bá a sọ ọ̀rọ̀ àṣírí, Joabu bá fi nǹkan gún un ní ikùn. Bẹ́ẹ̀ ni Abineri ṣe kú, nítorí pé ó pa Asaheli arakunrin Joabu. +Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó ní, “OLUWA mọ̀ pé, èmi ati àwọn eniyan mi kò lọ́wọ́ sí ikú Abineri rárá, ọwọ́ wa mọ́ patapata ninu ọ̀ràn náà. +Orí Joabu ati ìdílé baba rẹ̀ ni ẹ̀bi ìjìyà ikú yìí yóo dà lé. Láti ìrandíran rẹ̀, kò ní sí ẹnikẹ́ni tí kò ní kó àtọ̀sí, tabi kí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí kò ní jẹ́ pé iṣẹ́ obinrin nìkan ni wọn yóo lè ṣe, tabi kí wọ́n pa wọ́n lójú ogun, tabi kí wọ́n máa tọrọ jẹ.” +Ekeji ni Kileabu, ọmọ Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli. Ẹkẹta ni Absalomu, ọmọ Maaka, ọmọ Talimai, ọba Geṣuri. +Bẹ́ẹ̀ ni Joabu ati Abiṣai, arakunrin rẹ̀, ṣe pa Abineri tí wọ́n sì gbẹ̀san ikú Asaheli, arakunrin wọn, tí Abineri pa lójú ogun Gibeoni. +Dafidi pàṣẹ pé kí Joabu ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fa aṣọ wọn ya, kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ Abineri. Nígbà tí ó tó àkókò láti sìnkú Abineri, Dafidi ọba pàápàá tẹ̀lé òkú rẹ̀. +Heburoni ni wọ́n sin òkú Abineri sí, ọba sọkún létí ibojì rẹ̀, gbogbo àwọn eniyan sì sọkún pẹlu. +Dafidi kọ orin arò kan fún Abineri báyìí pé:“Kí ló dé tí Abineri fi kú bí aṣiwèrè? +Wọn kò dì ọ́ lọ́wọ́,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dì ọ́ lẹ́sẹ̀;o ṣubú bí ìgbà tí eniyan ṣubú níwájú ìkà.”Gbogbo eniyan sì tún bú sẹ́kún. +Gbogbo eniyan rọ Dafidi, pé kí ó jẹun ní ọ̀sán ọjọ́ náà ṣugbọn ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun bá fi ẹnu kan nǹkankan títí tí ilẹ̀ yóo fi ṣú. +Gbogbo àwọn eniyan ṣe akiyesi ohun tí ọba ṣe yìí, ó sì dùn mọ́ wọn. Gbogbo ohun tí ọba ṣe patapata ni ó dùn mọ́ àwọn eniyan. +Gbogbo àwọn eniyan Dafidi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni ó hàn sí gbangba pé, ọba kò lọ́wọ́ ninu pípa tí wọ́n pa Abineri. +Ọba bi àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé eniyan ńlá, ati alágbára kan ni ó ṣubú lónìí, ní ilẹ̀ Israẹli?” +Ó ní, “Agbára mi dínkù lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òróró ni a fi yàn mí ní ọba. Ìwà ipá àwọn ọmọ Seruaya yìí ti le jù fún mi. OLUWA nìkan ni ó lè san ẹ̀san fún eniyan burúkú gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀.” +Ẹkẹrin ni Adonija ọmọ Hagiti. Ẹkarun-un ni Ṣefataya ọmọ Abitali. +Ẹkẹfa sì ni Itireamu, ọmọ Egila. Heburoni ni wọ́n ti bí àwọn ọmọ náà fún Dafidi. +Ní àkókò tí ogun wà láàrin àwọn eniyan Dafidi ati àwọn eniyan Saulu, agbára Abineri bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i láàrin àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Saulu. +Ní ọjọ́ kan, Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu fi ẹ̀sùn kan Abineri pé ó bá obinrin Saulu kan, tí wọn ń pè ní Risipa, ọmọ Aya, lòpọ̀. +Ọ̀rọ̀ náà bí Abineri ninu gidigidi, ó bi Iṣiboṣẹti pé, “Ṣé o rò pé mo jẹ́ hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí Saulu laelae? Àbí ẹ̀yìn àwọn ará Juda ni ẹ rò pé mo wà ni? Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí Saulu baba rẹ, àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, èmi ni n kò sì ti jẹ́ kí apá Dafidi ká ọ. Ṣugbọn lónìí ńkọ́, ò ń fi ẹ̀sùn kàn mí nípa obinrin. +Kí Ọlọrun lù mí pa, bí n kò b�� ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ìkáwọ́ mi, láti mú ìlérí tí OLUWA ṣe fún Dafidi ṣẹ, +Àwọn Ọmọ Dafidi. +Nígbà tí Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu gbọ́ pé wọ́n ti pa Abineri ní Heburoni, ẹ̀rù bà á gidigidi, ìdààmú sì bá gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. +ẹni tí ó wá ròyìn ikú Saulu fún mi ní Sikilagi rò pé ìròyìn ayọ̀ ni òun mú wá fún mi, ṣugbọn mo ní kí wọn mú un kí wọ́n pa á. Ó jẹ èrè ìròyìn ayọ̀ rẹ̀, tí ó mú wá fún mi. +Báwo ni yóo ti burú tó fún àwọn ẹni ibi, tí wọ́n pa aláìṣẹ̀ sórí ibùsùn ninu ilé rẹ̀? Ṣé n kò ní gbẹ̀san pípa tí ẹ pa á lára yín, kí n sì pa yín rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé?” +Dafidi pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sì pa Rekabu ati Baana. Wọ́n gé ọwọ́ wọn, ati ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì so wọ́n kọ́ lẹ́bàá adágún tí ó wà ní Heburoni. Wọ́n gbé orí Iṣiboṣẹti, wọ́n sì sin ín sí ibojì Abineri ní Heburoni. +Iṣiboṣẹti ní àwọn ìjòyè meji kan, tí wọ́n jẹ́ aṣaaju fún àwọn tí wọ́n máa ń dánà káàkiri. Orúkọ ekinni ni Baana, ti ekeji sì ni Rekabu, ọmọ Rimoni, ará Beeroti, ti ẹ̀yà Bẹnjamini. (Ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ka Beeroti kún.) +Àwọn ará Beeroti ti sá lọ sí Gitaimu, ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní olónìí. +Jonatani ọmọ Saulu ní ọmọkunrin kan, tí ó yarọ, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mẹfiboṣẹti. Ọmọ ọdún marun-un ni, nígbà tí wọ́n mú ìròyìn ikú Saulu ati ti Jonatani wá, láti ìlú Jesireeli; ni olùtọ́jú rẹ̀ bá gbé e sá kúrò. Ibi tí ó ti ń fi ìkánjú gbé ọmọ náà sá lọ, ó já ṣubú, ó sì fi bẹ́ẹ̀ yarọ. +Ní ọjọ́ kan, Rekabu ati Baana, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti, gbéra, wọ́n lọ sí ilé Iṣiboṣẹti, wọ́n débẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀sán, ní àkókò tí Iṣiboṣẹti ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́. +Oorun ti gbé obinrin tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, tí ń fẹ́ ọkà lọ́wọ́ lọ, ó sùn lọ fọnfọn. Rekabu ati Baana bá rọra yọ́ wọlé. +Nígbà tí wọ́n wọlé, wọ́n bá a níbi tí ó sùn sí lórí ibùsùn ninu yàrá rẹ̀, wọ́n lù ú pa, wọ́n sì gé orí rẹ̀. Wọ́n gbé orí rẹ̀, wọ́n gba ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru ọjọ́ náà rìn. +Nígbà tí wọ́n dé Heburoni, wọ́n gbé orí rẹ̀ tọ Dafidi ọba lọ, wọ́n sì wí fún un pé, “Orí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ọ̀tá rẹ, tí ó ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ nìyí; oluwa mi, ọba, OLUWA ti mú kí ó ṣeéṣe láti gbẹ̀san, lára Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀.” +Ṣugbọn Dafidi dá wọn lóhùn pé, “OLUWA tí ó ti ń yọ mí ninu gbogbo ewu, ni mo fi búra pé, +Wọ́n Pa Iṣiboṣẹti. +Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli tọ Dafidi lọ ní Heburoni, wọ́n sọ fún un pé, “Ara kan náà ni wá, ẹ̀jẹ̀ kan náà sì ni gbogbo wa. +Agbára Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i, nítorí pé OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun wà pẹlu rẹ̀. +Hiramu ọba Tire rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi. Ó fi igi Kedari ranṣẹ sí i, pẹlu àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, ati àwọn tí wọn ń fi òkúta kọ́ ilé, pé kí wọ́n lọ kọ́ ààfin Dafidi. +Dafidi wá mọ̀ pé, OLUWA ti fi ìdí òun múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli, ó sì ti gbé ìjọba òun ga, nítorí Israẹli, àwọn eniyan rẹ̀. +Nígbà tí Dafidi kúrò ní Heburoni lọ sí Jerusalẹmu, ó fẹ́ àwọn obinrin mìíràn kún àwọn aya rẹ̀. Ó sì ní ọpọlọpọ ọmọ sí i, lọkunrin ati lobinrin. +Orúkọ àwọn tí wọ́n bí fún un ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣamua ati Ṣobabu, Natani, ati Solomoni; +Ibihari ati Eliṣua, Nefegi ati Jafia; +Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti. +Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi Dafidi jọba Israẹli, gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jáde lọ láti mú un, ṣugbọn Dafidi gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀ wá mú òun, ó bá lọ sí ibi ààbò. +Nígbà tí àwọn ará Filistia dé ibi àfonífojì Refaimu, wọ́n dúró níbẹ̀. +Dafidi bi OLUWA pé, “Ṣé kí n kọlu àwọn ará Filistia, ṣé o óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn?”OLUWA dá a lóhùn pé, “Kọlù wọ́n, n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn.” +Látẹ̀yìn wá, nígbà tí Saulu pàápàá wà lórí oyè, ìwọ ni o máa ń kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sógun. OLUWA sì ti ṣèlérí fún ọ pé, ìwọ ni o óo jẹ́ aṣiwaju àwọn eniyan rẹ̀, ati ọba wọn.” +Dafidi bá wá sí Baali Perasimu, ó sì ṣẹgun àwọn ará Filistia níbẹ̀. Ó ní, “Bí ìkún omi tí í ya bèbè rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fọ́n àwọn ọ̀tá mi ká níwájú mi.” Ó bá pe orúkọ ibẹ̀ ní Baali Perasimu. +Níbi tí àwọn ará Filistia ti ń sá lọ, wọ́n gbàgbé àwọn oriṣa wọn sílẹ̀, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì kó wọn lọ. +Àw���n ará Filistia pada, wọ́n tún dúró sí àfonífojì Refaimu. +Dafidi tún tọ OLUWA lọ láti bèèrè ohun tí yóo ṣe. OLUWA dá a lóhùn pé, “Má ṣe kọlù wọ́n níhìn-ín, ṣugbọn múra, kí o yípo lọ sẹ́yìn wọn, kí o sì kọlù wọ́n ní apá òdìkejì àwọn igi basamu. +Nígbà tí o bá gbọ́ ìró kan, tí ó bá dàbí ẹni pé, eniyan ń fi ẹsẹ̀ kilẹ̀ lọ lórí àwọn igi, ni kí o tó kọlù wọ́n, nítorí pé, OLUWA ti kọjá lọ níwájú rẹ láti ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Filistini.” +Dafidi ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un, ó sì pa àwọn ọmọ ogun Filistini láti Geba títí dé Geseri. +Gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli wá sí ọ̀dọ̀ ọba ní Heburoni, Dafidi ọba sì bá wọn dá majẹmu níbẹ̀ níwájú OLUWA. Wọ́n bá fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli. +Ẹni ọgbọ̀n ọdún ni, nígbà tí ó gorí oyè, ó sì jọba fún ogoji ọdún. +Ọdún meje ati oṣù mẹfa ni ó fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní Heburoni. Lẹ́yìn náà, ó wá sí Jerusalẹmu ó sì jọba lórí gbogbo Israẹli ati Juda fún ọdún mẹtalelọgbọn. +Nígbà tí ó yá, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Àwọn ará Jebusi tí wọn ń gbé ibẹ̀ nígbà náà wí fún Dafidi pé, “O kò lè wọ inú ìlú yìí wá, àwọn afọ́jú ati àwọn arọ lásán ti tó láti lé ọ dànù.” Wọ́n lérò pé Dafidi kò le ṣẹgun ìlú náà. +Ṣugbọn Dafidi jagun gba Sioni, ìlú olódi wọn. Sioni sì di ibi tí wọn ń pè ní ìlú Dafidi. +Dafidi bá sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ọjọ́ náà pé, “Jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ pa àwọn ará Jebusi gba ojú àgbàrá lọ pa àwọn afọ́jú ati àwọn arọ tí ọkàn Dafidi kórìíra.” (Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń wí pé, “Àwọn afọ́jú ati àwọn arọ kò ní lè wọ ilé OLUWA.”) +Lẹ́yìn tí Dafidi ti ṣẹgun ìlú olódi náà, ó ń gbé inú rẹ̀, ó sì yí orúkọ ibẹ̀ pada sí “Ìlú Dafidi”. Ó kọ́ ìlú náà yíká, bẹ̀rẹ̀ láti Milo, níbi tí wọ́n ti kún ilẹ̀ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn òkè náà. +Dafidi Di Ọba Israẹli ati ti Juda. +Dafidi tún pe gbogbo àwọn akikanju ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ; wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaarun (30,000). +Ọkàn rẹ̀ bá yipada, ó pinnu pé òun kò ní gbé e lọ sí Jerusalẹmu, ìlú Dafidi mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gbé e lọ sí ilé Obedi Edomu, ará ìlú Gati. +Àpótí ẹ̀rí OLUWA náà wà níbẹ̀ fún oṣù mẹta, OLUWA sì bukun Obedi Edomu ati ìdílé rẹ̀. +Wọ́n bá lọ sọ fún Dafidi pé, “OLUWA ti bukun Obedi Edomu, ati gbogbo ohun tí ó ní, nítorí pé àpótí ẹ̀rí OLUWA wà ní ilé rẹ̀.” Dafidi bá lọ gbé àpótí ẹ̀rí náà kúrò ní ilé rẹ̀ wá sí Jerusalẹmu, pẹlu àjọyọ̀ ńlá. +Lẹ́yìn tí àwọn tí wọ́n ru àpótí ẹ̀rí náà ti gbé ìṣísẹ̀ mẹfa, Dafidi dá wọn dúró, ó sì fi akọ mààlúù kan ati ọmọ mààlúù àbọ́pa kan rúbọ sí OLUWA. +Dafidi sán aṣọ mọ́dìí, ó sì ń jó pẹlu gbogbo agbára níwájú OLUWA. +Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA wọ Jerusalẹmu, pẹlu ìhó ayọ̀ ati ìró fèrè. +Bí wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí náà wọ inú ìlú Dafidi, Mikali ọmọ Saulu yọjú wo òde láti ojú fèrèsé, ó rí Dafidi ọba tí ó ń jó tí ó sì ń fò sókè níwájú OLUWA, Mikali sì kẹ́gàn rẹ̀ ninu ọkàn rẹ̀. +Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí náà wọnú ìlú, wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀, ninu àgọ́ tí Dafidi ti kọ́ sílẹ̀ fún un. Dafidi sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. +Nígbà tí ó rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan náà ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun. +Ó sì pín oúnjẹ fún gbogbo wọn, lọkunrin ati lobinrin. Ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìṣù àkàrà kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran kọ̀ọ̀kan, ati àkàrà tí wọ́n fi èso resini sí ninu. Lẹ́yìn náà, olukuluku lọ sí ilé. +Ó kó wọn lọ sí Baala ní Juda láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọrun wá sí Jerusalẹmu. Orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni wọ́n fi ń pe àpótí ẹ̀rí náà, ìtẹ́ rẹ̀ sì wà lórí àwọn Kerubu tí ó wà lókè àpótí náà. +Nígbà tí wọ́n parí, Dafidi pada sí ilé láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀. Mikali, ọmọ Saulu, bá lọ pàdé rẹ̀, ó ní, “Ọba Israẹli mà dárà lónìí! Ọba yán gbogbo aṣọ kúrò lára, bí aláìlóye eniyan níwájú àwọn iranṣẹbinrin àwọn iranṣẹ rẹ̀!” +Dafidi dá a lóhùn pé, “Ijó ni mò ń jó, níwájú OLUWA tí ó yàn mí dípò baba rẹ ati gbogbo ìdílé rẹ̀, láti fi mí ṣe alákòóso Israẹli, àwọn eniyan OLUWA. N óo tún máa jó níwájú OLUWA. +Kékeré ni èyí tí mo ṣe yìí, n óo máa ṣe jù bí mo ti ṣe yìí lọ. N kò ní jẹ́ nǹkankan lójú rẹ, ṣugbọn àwọn iranṣẹbinrin tí o sọ nípa wọn yìí, yóo bu ọlá fún mi.” +Mikali, ọmọbinrin Saulu, kò sì bímọ títí ó fi kú. +Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí jáde kúrò ní ilé Abinadabu tí ó wà lórí òkè, wọ́n sì gbé e ka orí kẹ̀kẹ́ tuntun kan. Usa ati Ahio ọmọ Abinadabu sì ń ti kẹ̀kẹ́ náà; +Ahio ni ó ṣáájú rẹ̀. +Dafidi ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí jó níwájú OLUWA, wọ́n sì ń kọrin pẹlu gbogbo agbára wọn. Wọ́n ń lu àwọn ohun èlò orin olókùn tí wọ́n ń pè ní hapu, ati lire; ati ìlù, ati ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ati aro. +Bí wọ́n ti dé ibi ìpakà Nakoni, àwọn mààlúù tí ń fa kẹ̀kẹ́ tí àpótí ẹ̀rí wà lórí rẹ̀ kọsẹ̀, Usa bá yára di àpótí ẹ̀rí náà mú. +Inú bí OLUWA sí Usa, OLUWA sì lù ú pa nítorí pé ó fi ọwọ́ kan àpótí ẹ̀rí náà. Usa kú sẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà. +Inú bí Dafidi gidigidi nítorí pé OLUWA lu Usa pa. Láti ìgbà náà ni wọ́n ti ń pe ibẹ̀ ní Peresi Usa, títí di òní olónìí. +Ẹ̀rù OLUWA ba Dafidi ní ọjọ́ náà, ó sì wí pé, “Báwo ni n óo ṣe gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA wá sọ́dọ̀ mi?” +Wọ́n Gbé Àpótí Ẹ̀rí Wá sí Jerusalẹmu. +Lẹ́yìn tí Dafidi ọba ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú ààfin rẹ̀, tí OLUWA ti fi ọkàn rẹ̀ balẹ̀, tí ó sì dáàbò bò ó lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, +N óo yan ibìkan fún Israẹli, àwọn eniyan mi, n óo sì fìdí wọn múlẹ̀ níbẹ̀. Wọn yóo máa gbé ilẹ̀ wọn, ẹnikẹ́ni kò sì ní ni wọ́n lára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ibi kò ní yọ wọ́n lẹ́nu mọ́ +bíi ti ìgbà tí mo yan àwọn onídàájọ́ fún Israẹli, àwọn eniyan mi. N óo fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.’ OLUWA sì tún tẹnu mọ́ ọn fún un pé, ‘Èmi fúnra mi ni n óo sọ ìdílé rẹ̀ di ìdílé ńlá. +Nígbà tí ó bá jáde láyé, tí ó bá sì re ibi àgbà rè, n óo fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ jọba, n óo sì jẹ́ kí ìjọba rẹ̀ lágbára. +Òun ni yóo kọ́ ilé fún mi, n óo sì rí i dájú pé ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba títí laelae. +N óo jẹ́ baba fún un, yóo sì jẹ́ ọmọ mi. Bí ó bá ṣẹ̀, n óo bá a wí, n óo sì jẹ ẹ́ níyà, bí baba ti í ṣe sí ọmọ rẹ̀. +Ṣugbọn n kò ní káwọ́ ìfẹ́ ńlá mi kúrò lára rẹ̀, bí mo ti ká a kúrò lára Saulu, tí mo sì yọ ọ́ lóyè, kí n tó fi í jọba. +Ìran rẹ kò ní parun, arọmọdọmọ rẹ ni yóo sì máa jọba títí ayé, ìjọba rẹ̀ yóo sì wà títí lae.’ ” +Natani bá tọ Dafidi lọ, ó sì sọ gbogbo nǹkan tí OLUWA fi hàn án fún un. +Dafidi ọba bá wọlé, ó jókòó níwájú OLUWA, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, “Ìwọ OLUWA Ọlọrun! Kí ni mo jẹ́, kí ni ilé mi jámọ́ tí o fi gbé mi dé ipò yìí? +Sibẹsibẹ, kò jẹ́ nǹkankan lójú rẹ, OLUWA Ọlọrun, o ti ṣèlérí fún èmi iranṣẹ rẹ nípa arọmọdọmọ mi, nípa ọjọ́ iwájú, o sì ti fihàn. +ọba wí fún Natani wolii pé, “Èmi ń gbé inú ààfin tí wọ́n fi igi kedari kọ́, ṣugbọn inú àgọ́ ni àpótí ẹ̀rí OLUWA wà!” +Kí ni mo tún lè sọ? O ṣá ti mọ̀ mí, èmi iranṣẹ rẹ, OLUWA Ọlọrun! +Nítorí ìlérí ati ìfẹ́ ọkàn rẹ ni o fi ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọnyi, kí iranṣẹ rẹ lè mọ̀ nípa wọn. +OLUWA Ọlọrun, o tóbi gan-an! Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, nítorí gbogbo ohun tí a ti fi etí wa gbọ́. +Kò sí orílẹ̀-èdè mìíràn ní gbogbo ayé, tí ó dàbí Israẹli, tí o yọ kúrò ní oko ẹrú láti fi wọ́n ṣe eniyan rẹ. O ti mú kí òkìkí Israẹli kàn nípa àwọn nǹkan ńláńlá, ati nǹkan ìyanu tí o ti ṣe fún wọn, nípa lílé àwọn eniyan orílẹ̀-èdè mìíràn jáde tàwọn ti oriṣa wọn, bí àwọn eniyan rẹ ti ń tẹ̀síwájú. +O ti yan àwọn ọmọ Israẹli fún ara rẹ, láti jẹ́ eniyan rẹ, o sì ti di Ọlọrun wọn títí lae. +“Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, jẹ́ kí ìlérí tí o ṣe nípa èmi ati arọmọdọmọ mi ṣẹ nígbà gbogbo, sì ṣe ohun tí o ti ṣèlérí pé o óo ṣe. +Orúkọ rẹ yóo sì lókìkí títí lae, gbogbo eniyan ni yóo sì máa wí títí lae pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni Ọlọrun Israẹli. O óo sì mú kí arọmọdọmọ mi wà níwájú rẹ títí laelae. +OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, pẹlu ìgboyà ni mo fi gbadura mi yìí sí ọ, nítorí pé o ti fi gbogbo nǹkan wọnyi han èmi iranṣẹ rẹ, o sì ti ṣèlérí pé o óo sọ ìdílé mi di ìdílé ńlá. +“Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ, o sì ti ṣèlérí ohun rere yìí fún iranṣẹ rẹ. +Mò ń bẹ̀bẹ̀ pé kí o bukun arọmọdọmọ mi, kí wọ́n lè máa bá ojurere rẹ pàdé nígbà gbogbo. Ìwọ OLUWA Ọlọrun ni o ṣèlérí yìí, ibukun rẹ yóo sì máa wà lórí arọmọdọmọ mi títí laelae.” +Natani dá a lóhùn pé, “Ṣe ohunkohun tí ó bá wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ.” +Ṣugbọn ní òru ọjọ́ náà, OLUWA wí fún Natani pé, +“Lọ sọ fún Dafidi iranṣẹ mi, pé, báyìí ni OLUWA wí, ‘Ṣé o fẹ́ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé ni? +Láti ìgbà tí mo ti gba àwọn ọmọ Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti títí di àkókò yìí, n kò fi ìgbà kan gbé inú ilé rí, inú àgọ́ ni mò ń gbé káàkiri. +Ninu gbogbo bí mo ti ṣe ń bá àwọn ọmọ Israẹli kiri, ǹjẹ́ mo bèèrè lọ́wọ́ ọ̀kan ninu àwọn olórí wọn tí mo yàn láti jẹ́ alákòóso àwọn eniyan mi, pé, Kí ló dé tí wọn kò fi igi kedari kọ́ ilé fún mi?’ +“Nítorí náà, sọ fún Dafidi iranṣẹ mi pé, ‘Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo mú un kúrò níbi tí ó ti ń ṣọ́ àwọn aguntan, ninu pápá, mo sì fi jọba Israẹli, àwọn eniyan mi. +Mo wà pẹlu rẹ̀ ní gbogbo ibi tí ó lọ, mo sì ń ṣẹgun gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ fún un, bí ó ti ń tẹ̀síwájú. N óo sọ ọ́ di olókìkí bí ọba tí ó lágbára jùlọ láyé. +Iṣẹ́ Tí Natani Jẹ́ fún Dafidi. +Lẹ́yìn náà, Dafidi ọba gbógun ti àwọn ará Filistia, ó ṣẹgun wọn, ó sì gba ìlú Mẹtẹgi-ama lọ́wọ́ wọn. +ó rán Joramu ọmọ rẹ̀ láti kí Dafidi ọba kú oríire, fún ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí Hadadeseri, nítorí pé Hadadeseri ti bá Toi jagun ní ọpọlọpọ ìgbà. Joramu mú ọpọlọpọ ẹ̀bùn tí wọ́n fi wúrà ṣe, ati ti fadaka, ati ti idẹ lọ́wọ́ fún Dafidi. +Dafidi ọba ya àwọn ẹ̀bùn náà sí mímọ́ fún ìlò ninu ilé OLUWA, pẹlu gbogbo fadaka ati wúrà tí ó rí kó láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun; +àwọn bíi: àwọn ará Edomu, àwọn ará Moabu, àwọn ará Amoni, àwọn ará Filistia, ati àwọn ará Amaleki; pẹlu ìkógun Hadadeseri, ọba Soba. +Dafidi túbọ̀ di olókìkí sí i nígbà tí ó pada dé, láti ibi tí ó ti lọ pa ẹgbaasan-an (18,000) ninu àwọn ará Edomu, ní Àfonífojì Iyọ̀. +Ó kọ́ ibùdó àwọn ọmọ ogun káàkiri ilẹ̀ Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì ń sin Dafidi. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ. +Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe jọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ń ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo sí gbogbo eniyan, nígbà gbogbo. +Joabu, ọmọ Seruaya ni balogun rẹ̀, Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni alákòóso gbogbo àwọn ìwé àkọsílẹ̀ rẹ̀. +Sadoku, ọmọ Ahitubu, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari ni alufaa, Seraaya ni akọ̀wé gbọ̀ngàn ìdájọ́ rẹ̀. +Bẹnaya, ọmọ Jehoiada ni olórí àwọn Kereti ati àwọn Peleti (tí ń ṣọ́ ààfin), àwọn ọmọ Dafidi ọkunrin ni wọ́n sì jẹ́ alufaa. +Ó ṣẹgun àwọn ará Moabu bákan náà, ó sì mú kí àwọn tí ó kó lẹ́rú ninu wọn dọ̀bálẹ̀ lórí ilẹ̀ ní ìlà mẹta, ó pa gbogbo àwọn tí wọ́n wà lórí ìlà meji, ó sì dá àwọn tí wọ́n dọ̀bálẹ̀ lórí ìlà kan sí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Moabu ṣe di ẹrú rẹ̀, tí wọ́n sì ń san owó ìṣákọ́lẹ̀ fún un. +Dafidi sì tún ṣẹgun Hadadeseri, ọmọ Rehobu, ọba Soba, bí ó tí ń lọ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó wà ní agbègbè odò Yufurate. +Ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ẹlẹ́ṣin ni Dafidi gbà lọ́wọ́ rẹ̀, ati ọ̀kẹ́ kan àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ rìn. Dafidi dá ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ṣugbọn ó dá ọgọrun-un (100) sí ninu wọn. +Nígbà tí àwọn ará Siria dé láti Damasku tí wọ́n ran Hadadeseri, ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi pa ẹgbaa mọkanla (22,000) ninu àwọn ọmọ ogun wọn. +Dafidi bá kọ́ àgọ́ àwọn ọmọ ogun kan sí Aramu, ní Damasku, gbogbo àwọn ará Siria sì ń sin Dafidi, wọ́n sì ń san owó ìṣákọ́lẹ̀ fún un. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ. +Dafidi gba àwọn apata wúrà tí àwọn ọ̀gágun Hadadeseri fi ń jagun, ó sì kó wọn wá sí Jerusalẹmu. +Bákan náà, Dafidi ọba kó ọpọlọpọ idẹ láti Bẹta ati Berotai, ìlú meji ninu àwọn ìlú tí ó wà lábẹ́ ìjọba Hadadeseri. +Nígbà tí Toi ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti ṣẹgun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, +Àwọn Ogun Tí Dafidi Jà ní Àjàṣẹ́gun. +Ní ọjọ́ kan, Dafidi bèèrè pé, “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu gbogbo ìdílé Saulu tí mo lè ṣoore fún nítorí Jonatani?” +Ìwọ, àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn iranṣẹ rẹ, ni ẹ óo máa ro gbogbo oko Saulu; ẹ ó máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn tí ẹ bá gbìn, kí ọmọ oluwa yín lè ní oúnjẹ tó, ṣugbọn Mẹfiboṣẹti alára, yóo máa wá jẹun lórí tabili mi nígbà gbogbo.” Àwọn ọmọkunrin tí Siba ní nígbà náà jẹ́ mẹẹdogun, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì jẹ́ ogún. +Siba dáhùn pé, gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ ni òun yóo ṣe.Mẹfiboṣẹti bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹun lórí tabili ọba, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ọba. +Ó ní ọdọmọkunrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Gbogbo àwọn ará ilé Siba sì di iranṣẹ Mẹfiboṣẹti. +Bẹ́ẹ̀ ni Mẹfiboṣẹti, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji ti rọ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé Jerusalẹmu, ó sì ń jẹun lọ́dọ̀ ọba nígbà gbogbo. +Ọkunrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Siba, tí ó ti jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Saulu nígbà ayé rẹ̀. Wọ́n pè é wá fún Dafidi, Dafidi sì bi í pé, “Ṣé ìwọ ni Siba?”Siba dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, oluwa mi, èmi ni.” +Ọba tún bi í pé, “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu ìdílé Saulu, tí mo lè fi àánú Ọlọrun hàn, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Ọlọrun pé n óo ṣe?”Siba dá a lóhùn pé, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Jonatani wà láàyè, ṣugbọn arọ ni.” +Ọba bi í pé, “Níbo ni ó wà?”Siba dá ọba lóhùn pé, “Ó wà ní ilé Makiri, ọmọ Amieli, ní Lodebari.” +Dafidi ọba bá ranṣẹ lọ mú un lati ilé Makiri ọmọ Amieli, ní Lodebari. +Nígbà tí Mẹfiboṣẹti, ọmọ Jonatani, tíí ṣe ọmọ ọmọ Saulu dé, ó wólẹ̀ níwájú Dafidi, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Dafidi pè é, ó ní, “Mẹfiboṣẹti!” ó sì dá a lóhùn pé, “Èmi, iranṣẹ rẹ nìyí.” +Dafidi wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, oore ni mo fẹ́ ṣe ọ́ nítorí Jonatani baba rẹ. Gbogbo ilẹ̀ tí ó ti jẹ́ ti Saulu baba baba rẹ rí, ni n óo dá pada fún ọ, a óo sì jọ máa jẹun lórí tabili mi nígbà gbogbo.” +Mẹfiboṣẹti tún wólẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó ní, “Kí ni èmi iranṣẹ rẹ fi sàn ju òkú ajá lọ, kí ló dé tí o fi ṣe mí ní oore tí ó tó báyìí?” +Ọba bá pe Siba, iranṣẹ Saulu, ó wí fún un pé, “Gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Saulu, ọ̀gá rẹ tẹ́lẹ̀, ati ti gbogbo ìdílé rẹ̀, ni n óo dá pada fún Mẹfiboṣẹti ọmọ ọmọ rẹ̀. +Dafidi ati Mẹfiboṣẹti. +Èmi Paulu, ati Silifanu, ati Timoti, ni à ń kọ ìwé yìí sí ìjọ Tẹsalonika, tíí ṣe ìjọ Ọlọrun Baba ati ti Jesu Kristi Oluwa. +nígbà tí Oluwa bá dé ní ọjọ́ náà láti gba ògo lọ́dọ̀ àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, nígbà tí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ yóo máa yẹ́ ẹ sí, nítorí wọ́n gba ẹ̀rí tí a jẹ́ fún wọn gbọ́. +Nítorí èyí ni a fi ń gbadura fun yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọrun wa lè kà yín yẹ fún ìpè tí ó pè yín, kí ó mú èrò gbogbo ṣẹ, kí ó sì fi agbára fun yín láti máa gbé ìgbé-ayé tí ó yẹ onigbagbọ; +kí ẹ lè yin orúkọ Oluwa wa Jesu lógo, kí òun náà sì yìn yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa ati ti Oluwa Jesu Kristi. +Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati Oluwa Jesu Kristi máa wà pẹlu yín. +Ẹ̀yin ará, ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí yín. Ó tọ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé igbagbọ yín ń tóbi sí i, ìfẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sí ara yín sì ń pọ̀ sí i. +Àwa fúnra wa ń fọ́nnu nípa yín láàrin àwọn ìjọ Ọlọrun. À ń ròyìn ìfaradà ati igbagbọ yín ninu gbogbo inúnibíni ati ìpọ́njú tí ẹ̀ ń faradà. +Ìfaradà yín jẹ́ ẹ̀rí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun láti kà yín yẹ fún ìjọba rẹ̀ tí ẹ̀ ń tìtorí rẹ̀ jìyà. +Nítorí ó tọ́ lójú Ọlọrun láti fi ìpọ́njú san ẹ̀san fún àwọn tí wọn ń pọn yín lójú, +ati láti fún ẹ̀yin tí wọn ń pọ́n lójú, ati àwa náà ní ìsinmi, nígbà tí Oluwa wa, Jesu, bá farahàn láti ọ̀run ninu ọwọ́ iná pẹlu àwọn angẹli tí wọ́n jẹ́ alágbára. +Nígbà náà ni yóo gbẹ̀san lára àwọn tí kò mọ Ọlọrun ati àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ ìyìn rere Oluwa wa Jesu. +Àwọn yìí ni wọn yóo gba ìdálẹ́bi sí ìparun ayérayé, wọn yóo sì kúrò níwájú Oluwa ati ògo agbára rẹ̀; +Ìkíni. +Ẹ̀yin ará, à ń bẹ̀ yín nípa ọ̀rọ̀ lórí ìgbà tí Oluwa yóo farahàn ati ìgbà tí yóo kó wa jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, +Yóo fi ọ̀nà àrékérekè burúkú lóríṣìíríṣìí tan àwọn ẹni ègbé jẹ, nítorí wọn kò ní ìfẹ́ òtítọ́, tí wọn ìbá fi rí ìgbàlà. +Nítorí èyí, Ọlọrun rán agbára ìtànjẹ sí wọn, kí wọ́n lè gba èké gbọ́, +kí gbogbo àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́ lè gba ìdálẹ́bi, àní, àwọn tí wọ́n ní inú dídùn sí ìwà ibi. +Ṣugbọn ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí yín, ẹ̀yin ará, àyànfẹ́ Oluwa, nítorí Ọlọrun ti yàn yín láti ìbẹ̀rẹ̀ wá láti gbà yín là nípa Ẹ̀mí t�� ó sọ yín di mímọ́, ati nípa gbígba òtítọ́ gbọ́. +Ọlọrun pè yín sí ipò yìí nípa iwaasu wa, kí ẹ lè jogún ògo Oluwa wa Jesu Kristi. +Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ di àwọn ẹ̀kọ́ tí a fi le yín lọ́wọ́ mú, kì báà ṣe àwọn tí a kọ yín nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tabi nípa ìwé tí à ń kọ si yín. Bẹ́ẹ̀ ni àwa náà gbà á. +Oluwa wa fúnrarẹ̀ ati Ọlọrun Baba wa, tí ó fẹ́ wa, tí ó fún wa ní ìtùnú ayérayé ati ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́, +yóo tù yín ninu, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ ninu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ati ọ̀rọ̀ rere. +ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín tètè mì, tabi kí èrò yín dàrú lórí ọ̀rọ̀ pé Ọjọ́ Oluwa ti dé. Kì báà jẹ́ pé ninu ọ̀rọ̀ wa tabi ninu Ẹ̀mí ni wọ́n ti rò pé a sọ ọ́, tabi bóyá ninu àlàyékálàyé kan tabi ìwé kan tí wọ́n rò pé ọ̀dọ̀ wa ni ó ti wá. +Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ lọ́nàkọnà nípa ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí kí ọjọ́ Oluwa tó dé, ọ̀tẹ̀ nípa ti ẹ̀sìn níláti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, kí Ẹni Ibi nnì, ẹni ègbé nnì sì farahàn. +Yóo lòdì sí ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti Ọlọrun tabi tí ó jẹ mọ́ ti ẹ̀sìn. Yóo gbé ara rẹ̀ ga ju èyíkéyìí ninu àwọn oriṣa lọ; yóo tilẹ̀ lọ jókòó ninu Tẹmpili Ọlọrun, yóo sì fi ara hàn pé òun ni Ọlọrun. +Ẹ ranti pé a ti sọ gbogbo èyí fun yín nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín. +Ǹjẹ́ nisinsinyii, ẹ mọ ohun tí ó ń ká a lọ́wọ́ kò, tí kò jẹ́ kí ó farahàn títí àkókò rẹ̀ yóo fi tó. +Nítorí nǹkan àṣírí kan tíí máa fa rúkèrúdò ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́, ṣugbọn ẹni tí ó ń ká a lọ́wọ́ kò wà, kò ì kúrò lọ́nà. +Nígbà tí ó bá kúrò lọ́nà tán ni Ọkunrin Burúkú nnì yóo wá farahàn. Ṣugbọn Oluwa Jesu yóo fi èémí ẹnu rẹ̀ pa á, yóo sọ ìfarahàn rẹ̀ di asán. +Nítorí Ẹni Burúkú yìí yóo farahàn pẹlu agbára Èṣù: yóo máa pidán, yóo ṣe iṣẹ́ àmì, yóo ṣe iṣẹ́ ìtànjẹ tí ó yani lẹ́nu. +Ẹni Ibi nnì. +Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ẹ máa gbadura fún wa, pé kí ọ̀rọ̀ Oluwa lè máa gbilẹ̀, kí ògo rẹ̀ máa tàn sí i, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láàrin yín. +Nítorí nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a pàṣẹ fun yín pé bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò ṣiṣẹ́, ẹ má jẹ́ kí ó jẹun. +Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ninu yín ń rìn ségesège, wọn kì í ṣiṣẹ́ rárá, ẹsẹ̀ ni wọ́n fi í máa wọ́lẹ̀ kiri. +A pàṣẹ fún irú àwọn bẹ́ẹ̀, a tún ń rọ̀ wọ́n ninu Oluwa Jesu Kristi pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ fún oúnjẹ ti ara wọn. +Ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí rere su yín í ṣe. +Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ wa ninu ìwé yìí, ẹ wo irú ẹni bẹ́ẹ̀ dáradára. Ẹ má ṣe bá a da nǹkankan pọ̀, kí ó lè yí pada. +Ẹ má mú un lọ́tàá, ṣugbọn ẹ máa gbà á níyànjú bí onigbagbọ. +Kí Oluwa alaafia fúnrarẹ̀ fun yín ní alaafia nígbà gbogbo lọ́nà gbogbo. Kí Oluwa wà pẹlu gbogbo yín. +Èmi Paulu ni mò ń fi ọwọ́ ara mi pàápàá kọ ìwé yìí. Bí èmi ti máa ń kọ̀wé nìyí. +Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu gbogbo yín. +Kí ẹ tún máa gbadura pé kí Ọlọrun gbà wá lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn ìkà, nítorí kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó gbàgbọ́. +Ṣugbọn olódodo ni Oluwa, òun ni yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóo sì pa yín mọ́ kúrò ninu ibi gbogbo. +A ní ìdánilójú ninu Oluwa nípa yín pé àwọn ohun tí a ti sọ, tí ẹ sì ń ṣe, ni ẹ óo máa ṣe. +Oluwa yóo tọ́ ọkàn yín láti mọ ìfẹ́ Ọlọrun ati ohun tí Kristi faradà nítorí yín. +Ẹ̀yin ará, à ń pàṣẹ fun yín ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí ẹ yẹra fún àwọn onigbagbọ tí wọn bá ń rìn ségesège, tí wọn kò tẹ̀lé ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ wa. +Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ bí ó ti yẹ kí ẹ ṣe àfarawé wa, nítorí a kò rìn ségesège nígbà tí a wà láàrin yín. +Bẹ́ẹ̀ ni a kò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni ninu yín lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣugbọn ninu làálàá ati ìṣòro ni à ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán-tòru, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára. +Kì í ṣe pé a kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹun lọ́dọ̀ yín; ṣugbọn a kò ṣe bẹ́ẹ̀ kí á lè fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ fun yín, kí ẹ lè fara wé wa. +Ẹ Gbadura fún Wa. +Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu, nípa ìfẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè tí ó wà ninu Kristi Jesu, èmi ni mò ń kọ ìwé yìí– +Ètò yìí ni ó wá hàn kedere nisinsinyii nípa ìfarahàn olùgbàlà wa Kristi Jesu, tí ó gba agbára lọ́wọ́ ikú, tí ó mú ìyè ati àìkú wá sinu ìmọ́lẹ̀ nípa ìyìn rere. +Ọlọrun yàn mí láti jẹ́ akéde ati aposteli ati olùkọ́ni. +Ìdí nìyí tí mo fi ń jìyà báyìí. Ṣugbọn ojú kò tì mí. Nítorí mo mọ ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé. Ó sì dá mi lójú pé ó lè pa ìṣúra tí mo fi pamọ́ sí i lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ ńlá náà. +Di àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ tí ó yẹ, tí o ti gbà láti ọ̀dọ̀ mi mú, pẹlu igbagbọ ati ìfẹ́ tí ó wà ninu Kristi Jesu. +Pa ìṣúra rere náà mọ́ pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ń gbé inú rẹ. +O kò ní ṣàìmọ̀ pé gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè Esia ti sá kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó fi mọ́ Fugẹlọsi ati Hemogenesi. +Kí Oluwa ṣàánú ìdílé Onesiforosi. Kò ní iye ìgbà tí ó ti tù mí ninu, ninu ìṣòro mi. Kò tijú pé ẹlẹ́wọ̀n ni mí. +Nígbà tí ó dé Romu, ó fi ìtara wá mi kàn, ó sì rí mi. +Kí Oluwa jẹ́ kí ó lè rí àánú rẹ̀ gbà ní ọjọ́ ńlá náà. Iṣẹ́ iranṣẹ tí ó ṣe ní Efesu kò ṣe àjèjì sí ìwọ alára. +Sí Timoti, àyànfẹ́ ọmọ mi. Kí oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu, Oluwa wa, wà pẹlu rẹ. +Nígbà tí mo bá ń ranti rẹ ninu adura mi tọ̀sán-tòru, èmi a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí mò ń sìn pẹlu ẹ̀rí-ọkàn mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba-ńlá mi ti ṣe. +Nígbà tí mo bá ranti ẹkún tí o sun, a dàbí kí n tún rí ọ, kí ayọ̀ mi lè di kíkún. +Mo ranti igbagbọ rẹ tí kò lẹ́tàn, tí ó kọ́kọ́ wà ninu Loisi ìyá-ìyá rẹ, ati ninu Yunisi ìyá rẹ, tí ó sì dá mi lójú pé ó wà ninu ìwọ náà. +Ìdí nìyí tí mo fi ń rán ọ létí pé kí o máa rú ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ Ọlọrun sókè, tí a fi fún ọ nípa ọwọ́ mi tí mo gbé lé ọ lórí. +Nítorí kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọrun fún wa bíkòṣe ẹ̀mí agbára ati ti ìfẹ́ ati ti ìkóra-ẹni-níjàánu. +Nítorí náà má ṣe tijú láti jẹ́rìí fún Oluwa wa tabi fún èmi tí mo wà lẹ́wọ̀n nítorí rẹ̀. Ṣugbọn gba ìjìyà tìrẹ ninu iṣẹ́ ìyìn rere pẹlu agbára Ọlọrun, +tí ó gbà wá là, tí ó pè wá láti ya ìgbé-ayé wa sọ́tọ̀. Kì í ṣe pé ìwà wa ni ó dára tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi pè wá. Ṣugbọn ó pè wá gẹ́gẹ́ bí ètò tí òun fúnrarẹ̀ ti ṣe, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó fi fún wa nípasẹ̀ Kristi Jesu láti ayérayé. +Ìdúpẹ́ ati Ọ̀rọ̀ Ìwúrí. +Nítorí náà, ìwọ ọmọ mi, jẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ tí ó wà ninu ìdàpọ̀ pẹlu Kristi Jesu sọ ọ́ di alágbára. +Nítorí náà, mo farada ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́, kí àwọn náà lè rí ìgbàlà tí ó wà ninu Kristi Jesu pẹlu ògo tí ó wà títí lae. +Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, pé,“Bí a bá bá a kú,a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀. +Bí a bá faradà á, a óo bá a jọba.Bí a bá sẹ́ ẹ,òun náà yóo sẹ́ wa. +Bí àwa kò bá tilẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé,òun ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nígbà gbogbo,nítorí òun kò lè tan ara rẹ̀ jẹ.” +Máa rán àwọn eniyan létí nípa nǹkan wọnyi. Kìlọ̀ fún wọn níwájú Ọlọrun pé kí wọn má máa jiyàn lórí oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ tí kò wúlò, tíí sìí máa da àwọn tí ó bá gbọ́ lọ́kàn rú. +Sa gbogbo ipá rẹ láti ṣe ara rẹ ní ẹni tí ó yege níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí kò ṣe ohun ìtìjú pamọ́, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ. +Yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán ati ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ràn irú ọ̀rọ̀ wọnyi túbọ̀ ń jìnnà sí ẹ̀sìn Ọlọrun ni. +Ọ̀rọ̀ wọn dàbí egbò-rírùn tí ó ń kẹ̀ siwaju. Irú wọn ni Himeneu ati Filetu, +àwọn tí wọ́n ti ṣìnà kúrò ninu òtítọ́, tí wọn ń sọ pé ajinde tiwa ti ṣẹlẹ̀, tí wọn ń mú kí igbagbọ ẹlòmíràn yẹ̀. +Ṣugbọn Ọlọrun ti fi ìpìlẹ̀ yìí lélẹ̀, tí ó dúró gbọningbọnin. Àkọlé tí a kọ sára èdìdì tí ó wà lára rẹ̀ nìyí: “Ọlọrun mọ àwọn ẹni tirẹ̀,” ati pé, “Gbogbo àwọn tí ó bá ń pe orúkọ Oluwa níláti kúrò ninu ibi.” +Àwọn ohun tí o gbọ́ láti ẹnu mi níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí, ni kí o fi lé àwọn olóòótọ́ eniyan lọ́wọ́, àwọn tí ó tó láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn. +Kì í ṣe àwọn ohun èèlò wúrà ati ti fadaka nìkan ni ó ń wà ninu ilé ńlá. Àwọn nǹkan tí wọ́n fi igi ati amọ̀ ṣe wà níbẹ̀ pẹlu. À ń lo àwọn kan fún nǹkan pataki; à ń lo àwọn mìíràn fún ohun tí kò ṣe pataki tóbẹ́ẹ̀. +Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ yóo di ohun èèlò tí ó níye lórí, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó wúlò fún baálé ilé. Yóo di ẹni tí ó ṣetán láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere. +Yẹra fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́. Máa lépa òdodo ati ìṣòtítọ́, ìfẹ́, ati alaafia, pẹlu àwọn tí ó ń képe Oluwa pẹlu ọkàn mímọ́. +Má bá wọn lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ati ọ̀rọ̀ òpè. Ranti pé ìjà ni wọ́n ń dá sílẹ̀. +Iranṣẹ Oluwa kò sì gbọdọ̀ jà. Ṣugbọn ó níláti máa ṣe jẹ́jẹ́ sí gbogbo eniyan, kí ó jẹ́ olùkọ́ni rere, tí ó ní ìfaradà. +Kí ó fi ìfarabalẹ̀ bá àwọn tí ó bá lòdì sí i wí, bóyá Ọlọrun lè fún wọn ní ọkàn ìrònúpìwàdà, kí wọ́n lè ní ìmọ̀ òtítọ́, +kí wọ́n lè bọ́ kúrò ninu tàkúté Satani, tí ó ti fi mú wọn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. +Farada ìpín tìrẹ ninu ìṣòro gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun Kristi Jesu. +Kò sí ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ tí ó gbọdọ̀ tún tojú bọ àwọn nǹkan ayé yòókù. Àníyàn rẹ̀ kanṣoṣo ni láti tẹ́ ọ̀gágun rẹ̀ lọ́rùn. +Kò sí ẹni tí ó bá ń súré ìje tí ó lè gba èrè àfi bí ó bá pa òfin iré ìje mọ́. +Àgbẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ lóko ni ó kọ́ ní ẹ̀tọ́ sí ìkórè oko. +Gba ohun tí mò ń sọ rò. Oluwa yóo jẹ́ kí ìtumọ̀ rẹ̀ yé ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. +Ranti Jesu Kristi tí a jí dìde kúrò ninu òkú, tí a bí ninu ìdílé Dafidi. Ìyìn rere tí mò ń waasu nìyí. +Ninu iṣẹ́ yìí ni mo ti ń jìyà títí mo fi di ẹlẹ́wọ̀n bí ọ̀daràn. Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè fi ẹ̀wọ̀n de ọ̀rọ̀ Ọlọrun. +Ọmọ-Ogun Rere Ti Kristi Jesu. +Kí o mọ èyí pé àkókò ìṣòro ni ọjọ́ ìkẹyìn yóo jẹ́. +Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, o ti tẹ̀lé ẹ̀kọ́ mi, ati ọ̀nà ìgbé-ayé mi, ète mi, ati igbagbọ mi, sùúrù mi, ìfẹ́ mi ati ìfaradà mi, +ninu inúnibíni, ninu irú ìyà tí ó bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu, ní Listira, ati oríṣìíríṣìí inúnibíni tí mo faradà. Oluwa ni ó yọ mí ninu gbogbo wọn. +Wọn yóo ṣe inúnibíni sí gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ gbé ìgbé-ayé olùfọkànsìn gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ. Inúnibíni níláti dé sí wọn. +Ṣugbọn yóo túbọ̀ máa burú sí i ni fún àwọn eniyan burúkú ati àwọn ẹlẹ́tàn: wọn yóo máa tan eniyan jẹ, eniyan yóo sì máa tan àwọn náà jẹ. +Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, dúró gbọningbọnin ninu àwọn ohun tí o ti kọ́, tí ó sì dá ọ lójú. Ranti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí o ti kọ́ wọn. +Nítorí láti ìgbà tí o ti wà ní ọmọde ni o ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n, tí o fi lè ní ìgbàlà nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu. +Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọrun, ó sì wúlò fún ẹ̀kọ́, fún ìbáwí, fún ìtọ́nisọ́nà, fún ìlànà nípa ìwà òdodo, +kí eniyan Ọlọrun lè jẹ́ ẹni tí ó pé, tí ó múra sílẹ̀ láti ṣe gbogbo iṣẹ́ rere. +Nítorí àwọn eniyan yóo wà tí ó jẹ́ pé ara wọn ati owó nìkan ni wọn óo fẹ́ràn. Wọn óo jẹ́ oníhàlẹ̀, onigbeeraga, ati onísọkúsọ. Wọn yóo máa ṣe àfojúdi sí àwọn òbí wọn. Wọn óo jẹ́ aláìmoore; aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, +onínú burúkú; akọ̀mágbẹ̀bẹ̀, abanijẹ́; àwọn tí kò lè kó ara wọn níjàánu, òǹrorò; àwọn tí kò fẹ́ ohun rere; +ọ̀dàlẹ̀, jàǹdùkú, àwọn tí ó jọ ara wọn lójú pupọ, àwọn tí wọ́n fẹ́ràn fàájì, dípò kí wọ́n fẹ́ràn Ọlọrun. +Ní òde, ara wọn dàbí olùfọkànsìn, ṣugbọn wọn kò mọ agbára ẹ̀sìn tòótọ́. Ìwọ jìnnà sí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀. +Ara wọn ni àwọn tíí máa tọ ojúlé kiri, tí wọn máa ń ki àwọn aṣiwèrè obinrin mọ́lẹ̀, àwọn obinrin tí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ̀ lẹ́wù, tí wọn ń ṣe oríṣìíríṣìí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. +Àwọn obinrin wọnyi ń kẹ́kọ̀ọ́ nígbà gbogbo, sibẹ wọn kò lè ní ìmọ̀ òtítọ́. +Bí Janesi ati Jamberesi ti tako Mose, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkunrin wọnyi tako òtítọ́. Orí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ ti kú, a sì ti ṣá wọn tì ní ti igbagbọ. +Ṣugbọn wọn kò lè máa bá irú ìwà bẹ́ẹ̀ lọ pẹ́ títí. Nítorí pé ìwà wèrè wọn yóo hàn kedere sí gbogbo eniyan, gẹ́gẹ́ bí ti Janesi ati Jamberesi ti hàn. +Ìwà tí Àwọn Eniyan Yóo Máa Hù ní Ọjọ́ Ìkẹyìn. +Mò ń kìlọ̀ fún ọ níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, tí ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ àwọn alààyè ati àwọn òkú; mò ń kì ọ́ nílọ̀ nítorí ìfarahàn rẹ̀ ati ìjọba rẹ̀. +Demasi ti fi mí sílẹ̀ nítorí ó fẹ́ràn nǹkan ayé yìí. Ó ti lọ sí Tẹsalonika. Kirẹsẹnsi ti lọ sí Galatia. Titu ti lọ sí Dalimatia. +Luku nìkan náà ni ó kù lọ́dọ̀ mi. Mú Maku lọ́wọ́ bí o bá ń bọ̀ nítorí ó wúlò fún mi bí iranṣẹ. +Mo ti rán Tukikọsi lọ sí Efesu. +Nígbà tí o bá ń bọ̀, bá mi mú agbádá tí mo fi sọ́dọ̀ Kapu ní Tiroasi bọ̀. Bá mi mú àwọn ìwé mi náà bọ̀, pataki jùlọ àwọn ìwé aláwọ mi. +Alẹkisanderu, alágbẹ̀dẹ bàbà fi ojú mi rí nǹkan! Kí Oluwa san ẹ̀san fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. +Kí ìwọ náà ṣọ́ra lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí títa ni ó ń tako àwọn ohun tí à ń sọ. +Nígbà tí mo níláti jà fún ara mi ní ẹẹkinni, kò sí ẹni tí ó yọjú láti gbèjà mi: gbogbo wọn ni wọ́n fi mí sílẹ̀. Kí Ọlọrun má kà á sí wọn lọ́rùn. +Ṣugbọn Oluwa dúró tì mí, ó fún mi lágbára tí mo fi waasu ìyìn rere lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu fi gbọ́. Bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe bọ́ lẹ́nu kinniun. +Oluwa yóo yọ mí kúrò ninu iṣẹ́ burúkú gbogbo, yóo sì gbà mí sinu ìjọba rẹ̀ ní ọ̀run. Tirẹ̀ ni ògo lae ati laelae. Amin. +Kí Pirisila ati Akuila ati ìdílé Onesiforosi. +Waasu ọ̀rọ̀ náà. Tẹnumọ́ ọn ní àkókò tí ó wọ̀ ati àkókò tí kò wọ̀. Máa báni wí. Máa gbani ní ìyànjú. Máa gbani ní ìmọ̀ràn, pẹlu ọpọlọpọ sùúrù tí ó yẹ kí ẹni tí yóo bá kọ́ eniyan lẹ́kọ̀ọ́ dáradára ní. +Erastu ti dúró ní Kọrinti. Mo fi Tirofimọsi sílẹ̀ ní Miletu pẹlu àìlera. +Sa ipá rẹ láti wá kí ó tó di àkókò òtútù.Yubulọsi kí ọ, ati Pudẹsi, Linọsi, Kilaudia ati gbogbo àwọn arakunrin. +Kí Oluwa wà pẹlu ẹ̀mí rẹ.Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo yín. +Àkókò ń bọ̀ tí àwọn eniyan kò ní fẹ́ fetí sí ẹ̀kọ́ tí ó yè. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara wọn ni wọn yóo tẹ̀lé, tí wọn yóo kó àwọn olùkọ́ tira, tí wọn yóo máa sọ ohun tí wọn máa ń fẹ́ gbọ́ fún wọn. +Wọn óo di etí wọn sí òtítọ́; ìtàn àhesọ ti ara wọn ni wọn yóo máa gbọ́. +Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, fi ara balẹ̀ ninu ohun gbogbo. Farada ìṣòro. Ṣe iṣẹ́ ìyìn rere. Má fi ohunkohun sílẹ̀ láì ṣe ninu iṣẹ́ iranṣẹ rẹ. +Ní tèmi, a ti fi mí rúbọ ná. Àkókò ati fi ayé sílẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tó. +Mo ti ja ìjà rere. Mo ti dé òpin iré ìje náà. +Nisinsinyii adé òdodo náà wà nílẹ̀ fún mi, tí Oluwa onídàájọ́ òdodo yóo fún mi ní ọjọ́ náà. Èmi nìkan kọ́ ni yóo sì fún, yóo fún gbogbo àwọn tí wọn ń fi tìfẹ́tìfẹ́ retí ìfarahàn rẹ̀. +Sa gbogbo ipá rẹ láti tètè wá sọ́dọ̀ mi. +Ọ̀rọ̀ Ìparí. +Èmi, Alàgbà, ni mo kọ ìwé yìí sí ọ, Gaiyu olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ràn nítòótọ́. +Nítorí náà, nígbà tí mo bá dé, n óo ranti àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ń ṣe, tí ó ń sọ ìsọkúsọ nípa mi. Kò fi ọ̀ràn mọ bẹ́ẹ̀; kò gba àwọn arakunrin tí wọ́n wá, àwọn tí wọ́n sì fẹ́ gbà wọ́n, kò jẹ́ kí wọ́n gbà wọ́n, ó tún fẹ́ yọ wọ́n kúrò ninu ìjọ! +Olùfẹ́, má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú, ṣugbọn tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere. Ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ẹni tí ó bá ń ṣe rere ti wá. Ẹni tí ó bá ń ṣe burúkú kò mọ Ọlọrun. +Gbogbo eniyan ni wọ́n ń ròyìn Demeteriu ní rere. Òtítọ́ pàápàá ń jẹ́rìí rẹ̀. Èmi náà jẹ́rìí sí i, o sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí mi. +Mo ní ohun pupọ tí mo fẹ́ bá ọ sọ, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé. +Mo ní ìrètí ati rí ọ láìpẹ́, nígbà náà a óo lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju. +Kí alaafia máa bá ọ gbé. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa níhìn-ín kí ọ. Bá wa kí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́kọ̀ọ̀kan. +Olùfẹ́, mo gbadura pé kí ó dára fún ọ ní gbogbo ọ̀nà ati pé kí o ní ìlera, gẹ́gẹ́ bí o ti ní ìlera ninu ẹ̀mí. +Inú mi dùn nígbà tí àwọn arakunrin dé, tí wọ́n ròyìn rẹ pé o ṣe olóòótọ́ sí ọ̀nà òtítọ́, ati pé ò ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́. +Ayọ̀ mi kì í lópin, nígbà tí mo bá gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́. +Olùfẹ́, ohun rere ni ò ń ṣe fún àwọn arakunrin, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ àlejò. +Níwájú gbogbo ìjọ níhìn-ín wọ́n jẹ́rìí sí oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ ninu ìrìn àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ fún òṣìṣẹ́ Ọlọrun. +Nítorí pé orúkọ Jesu ni ó mú wọn máa rin ìrìn àjò láì gba ohunkohun lọ́wọ́ àwọn alaigbagbọ. +Ó yẹ kí á máa ran irú wọn lọ́wọ́ kí á lè jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu wọn ninu iṣẹ́ òtítọ́. +Mo kọ ìwé kan sí ìjọ ṣugbọn Diotirefe tí ó fẹ́ ipò aṣiwaju láàrin ìjọ kò gba ohun tí mo sọ. +Ìkíni. +Tiofilu mi ọ̀wọ́n: Ninu ìwé mi àkọ́kọ́, mo ti sọ nípa gbogbo ohun tí Jesu ṣe ati ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ àwọn eniyan, +Bí wọ́n ti tẹjú mọ́ òkè bí ó ti ń lọ, àwọn ọkunrin meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun dúró tì wọ́n. +Wọ́n ní, “Ẹ̀yin ará Galili, kí ló dé tí ẹ fi dúró tí ẹ̀ ń wòkè bẹ́ẹ̀? Jesu kan náà, tí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, lọ sí ọ̀run yìí, yóo tún pada wá bí ẹ ṣe rí i tí ó ń lọ sí ọ̀run.” +Wó��n pada sí Jerusalẹmu láti orí òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. Òkè náà súnmọ́ Jerusalẹmu, kò tó ibùsọ̀ kan sí ìlú. +Nígbà tí wọ́n wọ inú ilé, wọ́n lọ sí iyàrá òkè níbi tí wọn ń gbé. Àwọn tí wọ́n jọ ń gbé ni Peteru, Johanu, Jakọbu, Anderu, Filipi, Tomasi, Batolomiu, Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni ti ẹgbẹ́ Seloti ati Judasi ọmọ Jakọbu. +Gbogbo wọn ń fi ọkàn kan gbadura nígbà gbogbo pẹlu àwọn obinrin ati Maria ìyá Jesu ati àwọn arakunrin Jesu. +Ní ọjọ́ kan, Peteru dìde láàrin àwọn arakunrin tí wọ́n tó ọgọfa eniyan, ó ní, +“Ẹ̀yin ará, dandan ni pé kí ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ ninu Ìwé Mímọ́ láti ẹnu Dafidi ṣẹ, nípa ọ̀rọ̀ Judasi tí ó ṣe amọ̀nà àwọn tí ó mú Jesu. +Nítorí ọ̀kan ninu wa ni, ó sì ní ìpín ninu iṣẹ́ yìí.” +(Ó ra ilẹ̀ kan pẹlu owó tí ó gbà fún ìwà burúkú rẹ̀, ni ó bá ṣubú lulẹ̀, ikùn rẹ̀ sì bẹ́, gbogbo ìfun rẹ̀ bá tú jáde. +Gbogbo àwọn eniyan tí ó ń gbé Jerusalẹmu ni ó mọ̀ nípa èyí. Wọ́n bá ń pe ilẹ̀ náà ní “Akelidama” ní èdè wọn. Ìtumọ̀ èyí ni “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.”) +títí di ọjọ́ tí a gbé e lọ sókè ọ̀run lẹ́yìn tí ó ti pàṣẹ ohun tí ó fẹ́, nípa Ẹ̀mí Mímọ́, fún àwọn aposteli tí ó ti yàn. +“Ọ̀rọ̀ náà rí bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Ìwé Orin Dafidi pé, ‘Kí ibùgbé rẹ̀ di ahoro,kí ẹnikẹ́ni má gbé ibẹ̀.’Ati pé,‘Kí á fi ipò rẹ̀ fún ẹlòmíràn.’ +“Nítorí náà, ẹ̀tọ́ ni kí á yan ẹnìkan ninu àwọn tí ó ti wà pẹlu wa ní gbogbo àkókò tí Jesu Oluwa ti ń wọlé, tí ó ń jáde pẹlu wa, láti àkókò tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi títí di ọjọ́ tí a fi mú Jesu kúrò lọ́dọ̀ wa, kí olúwarẹ̀ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí ajinde Jesu, kí ó sì di ọ̀kan ninu wa.” +Wọ́n bá gbé ẹni meji siwaju: Josẹfu tí à ń pè ní Basaba, tí ó tún ń jẹ́ Jusitu, ati Matiasi. +Wọ́n gbadura pé, “Ìwọ Oluwa, Olùmọ̀ràn gbogbo eniyan, fi ẹni tí o bá yàn ninu àwọn mejeeji yìí hàn, +kí ó lè gba iṣẹ́ yìí ati ipò aposteli tí Judasi fi sílẹ̀ láti lọ sí ààyè tirẹ̀.” +Wọ́n bá ṣẹ́ gègé. Gègé bá mú Matiasi. Ó bá di ọ̀kan ninu àwọn aposteli mọkanla. +Àwọn aposteli yìí ni ó fi ara rẹ̀ hàn láàyè lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀ pẹlu ẹ̀rí tí ó dájú. Wọ́n rí i níwọ̀n ogoji ọjọ́, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti ìjọba Ọlọrun. +Nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ wọn, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn má kúrò ní Jerusalẹmu. Ó ní, “Ẹ dúró títí ìlérí tí Baba mí ṣe yóo fi ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ tí mo sọ fun yín. +Nítorí omi ni Johanu fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́, ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ ni a óo fi ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín láìpẹ́ jọjọ.” +Ní ọjọ́ kan tí gbogbo wọn péjọ, wọ́n bi í pé, “Oluwa, ṣé àkókò tó nisinsinyii tí ìwọ yóo gba ìjọba pada fún Israẹli?” +Ó dá wọn lóhùn pé, “Kì í ṣe tiyín láti mọ àkókò tabi ìgbà tí Baba ti fi sí ìkáwọ́ ara rẹ̀ nìkan ṣoṣo. +Ṣugbọn ẹ̀yin yóo gba agbára nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé yin. Ẹ óo wá máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo Judia ati ní Samaria ati títí dé òpin ilẹ̀ ayé.” +Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, bí wọ́n ti ń wò ó, a gbé e sókè, ìkùukùu bò ó, wọn kò sì rí i mọ́. +Jesu Ṣe Ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́. +Ọkunrin kan wà ní Kesaria tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kọniliu. Ó jẹ́ balogun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ tí à ń pè ní Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Itali. +Ebi dé sí i, ó wá ń wá nǹkan tí yóo jẹ. Bí wọ́n ti ń tọ́jú oúnjẹ lọ́wọ́, Peteru bá rí ìran kan. +Ó rí ọ̀run tí ó pínyà, tí nǹkankan bí aṣọ tí ó fẹ̀, tí ó ní igun mẹrin, ń bọ̀ wálẹ̀, títí ó fi dé ilẹ̀. +Gbogbo ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹrin ati oríṣìíríṣìí ẹranko tí ó ń fi àyà fà, ati ẹyẹ ojú ọ̀run ni ó wà ninu rẹ̀. +Ó wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó ń bá a sọ̀rọ̀, ó ní, “Peteru dìde, pa ẹran kí o jẹ ẹ́!” +Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Èèwọ̀ Oluwa! N kò jẹ ẹrankẹ́ran tabi ẹran àìmọ́ kan rí.” +Ohùn náà tún dún létí rẹ̀ lẹẹkeji pé, “Ohun tí Ọlọrun bá ti sọ di mímọ́, o kò gbọdọ̀ pè é ní ohun àìmọ́!” +Èyí ṣẹlẹ̀ lẹẹmẹta. Lẹsẹkẹsẹ a tún gbé aṣọ náà lọ sókè ọ̀run. +Ìran tí Peteru rí yìí rú u lójú. Bí ó ti ń rò ó pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí òun rí yìí, àwọn tí Kọniliu rán sí i ti wádìí ibi tí ilé Simoni wà, wọ́n ti dé ẹnu ọ̀nà. +Wọ́n ké “Àgò!” wọ́n sì ń bèèrè bí Simoni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru bá dé sibẹ. +Bí Peteru ti ń ronú lórí ìran y��í, Ẹ̀mí sọ fún un pé, “Àwọn ọkunrin mẹta ń wá ọ. +Olùfọkànsìn ni. Òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì bẹ̀rù Ọlọrun. A máa ṣàánú àwọn eniyan lọpọlọpọ, a sì máa gbadura sí Ọlọrun nígbà gbogbo. +Dìde, lọ sí ìsàlẹ̀, kí o bá wọn lọ láì kọminú nítorí èmi ni mo rán wọn.” +Nígbà tí Peteru dé ìsàlẹ̀, ó wí fún àwọn ọkunrin náà pé, “Èmi tí ẹ̀ ń wá nìyí, kí ni ẹ̀ ń fẹ́ o?” +Wọ́n bá dáhùn pé, “Kọniliu ọ̀gágun ni ó rán wa wá; eniyan rere ni, ó sì bẹ̀rù Ọlọrun tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ọmọ Juu fi lè jẹ́rìí sí i. Angẹli Oluwa ni ó sọ fún un pé kí ó ranṣẹ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀, kí ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.” +Ni Peteru bá pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò.Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó dìde, ó bá wọn lọ. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ìjọ ní Jọpa sì tẹ̀lé wọn. +Ní ọjọ́ keji tí wọ́n gbéra ní Jọpa ni wọ́n dé Kesaria. Kọniliu ti ń retí wọn. Ó ti pe àwọn ẹbí ati àwọn tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ. +Bí Peteru ti fẹ́ wọlé, Kọniliu lọ pàdé rẹ̀. Ó kúnlẹ̀, ó sì foríbalẹ̀. +Ṣugbọn Peteru fà á dìde, ó ní, “Dìde! Eniyan ni èmi náà.” +Bí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó bá a wọlé. Ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó ti péjọ. +Ó sọ fún wọn pé, “Ó ye yín pé ó lòdì sí òfin wa pé kí ẹni tíí ṣe Juu kí ó ní nǹkan í ṣe pẹlu ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, tabi kí ó lọ bẹ̀ ẹ́ wò ninu ilé rẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mí pé n kò gbọdọ̀ pe ẹnikẹ́ni ni eniyan lásán tabi aláìmọ́. +Ìdí tí mo ṣe wá láì kọminú nìyí nígbà tí o ranṣẹ sí mi. Mo wá fẹ́ mọ ìdí rẹ̀ tí o fi ranṣẹ sí mi.” +Ní ọjọ́ kan, ní nǹkan agogo mẹta ọ̀sán, ó rí ìran kan. Angẹli Ọlọrun wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Kọniliu!” +Kọniliu dáhùn pé, “Ní ijẹrin, ní déédé àkókò yìí, mo ń gbadura ninu ilé mi ní agogo mẹta ọ̀sán. Ọkunrin kan bá yọ sí mi, ó wọ aṣọ dídán. +Ó ní, ‘Kọniliu, Ọlọrun ti gbọ́ adura rẹ, ó sì ti ranti iṣẹ́ àánú rẹ. +Nítorí náà, ranṣẹ lọ sí Jọpa, kí o lọ pe Simoni tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Peteru wá. Ó dé sílé Simoni tí ń ṣe òwò awọ, létí òkun.’ +Lẹsẹkẹsẹ ni mo bá ranṣẹ sí ọ. O ṣeun tí o wá. Nisinsinyii gbogbo wa wà níwájú Ọlọrun láti gbọ́ ohun gbogbo tí Oluwa ti pa láṣẹ fún ọ láti sọ.” +Peteru bá tẹnu bọ̀rọ̀. Ó ní, “Ó wá yé mi gan-an pé Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju. +Ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣe rere ni yóo fà mọ́ra láì bèèrè orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́. +Ẹ mọ iṣẹ́ tí ó rán sí àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ ìyìn rere alaafia nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tíí ṣe Oluwa gbogbo eniyan. +Ẹ mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo Judia. Ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili lẹ́yìn ìrìbọmi tí Johanu ń sọ pé kí àwọn eniyan ṣe. +Ẹ mọ̀ nípa Jesu ará Nasarẹti, bí Ọlọrun ti ṣe yàn án, tí ó fún un ní Ẹ̀mí Mímọ́ ati agbára; bí ó ti ṣe ń lọ káàkiri tí ó ń ṣe rere, tí ó ń wo gbogbo àwọn tí Satani ti ń dá lóró sàn, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. +Àwa yìí ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe ní ilẹ̀ àwọn Juu ati ní Jerusalẹmu. Wọ́n kan ọkunrin yìí mọ́ agbelebu. +Kọniliu bá tẹjú mọ́ ọn. Ẹ̀rù bà á, ó ní, “Kí ló dé, alàgbà?”Angẹli yìí bá sọ fún un pé, “Adura rẹ ti gbà; iṣẹ́ àánú rẹ ti gòkè lọ siwaju Ọlọrun. Ọlọrun sì ti ranti rẹ. +Ṣugbọn Ọlọrun jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, ó sì jẹ́ kí eniyan rí i. +Kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó rí i bíkòṣe àwọn ẹlẹ́rìí tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwa tí a bá a jẹ, tí a bá a mu lẹ́yìn tí ó jinde kúrò ninu òkú. +Ó wá pàṣẹ fún wa láti waasu fún àwọn eniyan, kí á fi yé wọn pé Jesu yìí ni ẹni tí Ọlọrun ti yàn láti jẹ́ onídàájọ́ àwọn tí ó ti kú ati àwọn tí ó wà láàyè. +Òun ni gbogbo àwọn wolii ń jẹ́rìí sí, tí wọ́n sọ pé gbogbo ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ yóo ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní orúkọ rẹ̀.” +Bí Peteru ti ń sọ̀rọ̀ báyìí lọ́wọ́, kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. +Ẹnu ya àwọn onigbagbọ tí wọ́n jẹ́ Juu tí wọ́n bá Peteru wá nítorí àwọn tí kì í ṣe Juu rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ gbà lọ́fẹ̀ẹ́ ati lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. +Wọ́n gbọ́ tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí èdè sọ̀rọ̀, tí wọn ń yin Ọlọrun fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀. Peteru bá bèèrè pé, +“Ta ló rí ohun ìdíwọ́ kan, ninu pé kí á ṣe ìrìbọmi fún àwọn wọnyi, tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa náà ti gbà á?” +Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi ní orúkọ Jesu Kristi. Wọ́n bá bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ díẹ̀. +Nisinsinyii wá rán àwọn kan lọ sí Jọpa, kí wọn lọ pe ẹnìkan tí ń jẹ́ Simoni, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru, kí ó wá. +Ó dé sílé ẹnìkan tí ń jẹ́ Simoni, tí ń ṣe òwò awọ, tí ilé rẹ̀ wà létí òkun.” +Bí angẹli tí ó ń bá a sọ̀rọ̀ ti lọ tán, ó pe meji ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, ọ̀kan ninu àwọn tí ó máa ń dúró tì í tímọ́tímọ́. +Ó ròyìn ohun gbogbo fún wọn, ó bá rán wọn lọ sí Jọpa. +Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń bá ìrìn àjò wọn lọ, tí wọ́n súnmọ́ Jọpa, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbadura ní nǹkan agogo mejila ọ̀sán. +Ìtàn Peteru ati Kọniliu. +Àwọn aposteli ati àwọn onigbagbọ yòókù tí ó wà ní Judia gbọ́ pé àwọn tí kì í ṣe Juu náà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun. +Ẹẹmẹta ni ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ni nǹkankan bá tún fa gbogbo wọn pada sí ọ̀run. +Lákòókò náà gan-an ni àwọn ọkunrin mẹta tí a rán sí mi láti Kesaria dé ilé tí mo wà. +Ẹ̀mí wá sọ fún mi pé kí n bá wọn lọ láì kọminú. Mẹfa ninu àwọn arakunrin bá mi lọ. A bá wọ ilé ọkunrin náà. +Ó sọ fún wa bí òun ti ṣe rí angẹli tí ó dúró ninu ilé òun tí ó sọ pé, ‘Ranṣẹ lọ sí Jọpa, kí o pe Simoni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru wá. +Òun ni yóo sọ ọ̀rọ̀ fún ọ nípa bí ìwọ ati ìdílé rẹ yóo ṣe ní ìgbàlà.’ +Bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé wọn bí ó ti bà lé wa ní àkọ́kọ́. +Ó mú mi ranti ọ̀rọ̀ Oluwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Omi ni Johanu fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fun yín, ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ ni a óo fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ yín.’ +Nítorí náà bí Ọlọrun bá fún wọn ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan náà bí ó ti fún àwa tí a gba Oluwa Jesu Kristi gbọ́, tèmi ti jẹ́, tí n óo wá dí Ọlọrun lọ́nà?” +Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò tún ní ìkọminú mọ́ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Wọ́n bá ń yin Ọlọrun. Wọ́n ní, “Èyí ni pé Ọlọrun ti fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù náà ní anfaani láti ronupiwada kí wọ́n lè ní ìyè.” +Àwọn tí ó túká nígbà inúnibíni tí ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò Stefanu dé Fonike ní Kipru ati Antioku. Wọn kò bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ ìyìn rere àfi àwọn Juu nìkan. +Nígbà tí Peteru pada dé Jerusalẹmu, àwọn onigbagbọ tí ó jẹ́ Juu dá àríyànjiyàn sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà. +Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan ninu àwọn ará Kipru ati Kirene dé Antioku, wọ́n bá àwọn ará Giriki sọ̀rọ̀, wọ́n ń waasu Oluwa Jesu fún wọn. +Agbára Oluwa hàn ninu iṣẹ́ wọn. Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n gbàgbọ́, tí wọ́n sì yipada sí Oluwa. +Ìròyìn dé etí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu nípa wọn. Wọ́n bá rán Banaba sí Antioku. +Nígbà tí ó dé, tí ó rí bí Ọlọrun ti ṣiṣẹ́ láàrin wọn, inú rẹ̀ dùn. Ó gba gbogbo wọn níyànjú pé kí wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn dúró ti Oluwa pẹlu òtítọ́. +Nítorí Banaba jẹ́ eniyan rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó sì gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó di onigbagbọ. +Banaba bá wá Paulu lọ sí Tasu. +Nígbà tí ó rí i, ó mú un wá sí Antioku; fún ọdún kan gbáko ni àwọn mejeeji fi wà pẹlu ìjọ, tí wọn ń kọ́ ọpọlọpọ eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Ní Antioku ni a ti kọ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi ní “Kristẹni.” +Ní àkókò náà, àwọn wolii kan wá láti Jerusalẹmu sí Antioku. +Ọ̀kan ninu wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agabu bá dìde. Ẹ̀mí gbé e láti sọ pé ìyàn ńlá yóo mú ní gbogbo ayé. (Èyí ṣẹlẹ̀ ní ayé ọba Kilaudiu.) +Ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi bá pinnu pé olukuluku àwọn yóo sa gbogbo agbára rẹ̀ láti fi nǹkan ranṣẹ sí àwọn onigbagbọ tí ó ń gbé Judia. +Wọ́n ní, “O wọlé tọ àwọn eniyan tí kò kọlà lọ, o sì bá wọn jẹun!” +Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n kó nǹkan rán Banaba ati Saulu sí wọn. +Peteru bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ro gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn lẹ́sẹẹsẹ. +Ó ní, “Ìlú Jọpa ni mo wà tí mò ń gbadura, ni mo bá rí ìran kan. Nǹkankan tí ó dàbí aṣọ tí ó fẹ̀, tí wọ́n so ní igun mẹrin ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run títí ó fi dé ọ̀dọ̀ mi. +Mo tẹjú mọ́ ọn láti wo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Mo bá rí àwọn ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹrin ati àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati àwọn ẹranko tí ń fi àyà wọ́, ati àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. +Mo wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó sọ fún mi pé, ‘Peteru, dìde, pa àwọn ẹran tí o bá fẹ́, kí o sì jẹ.’ +Ṣugbọn mo ní, ‘Èèwọ̀, Oluwa! N kò jẹ ẹrankẹ́ran tabi ẹran àìmọ́ kan rí.’ +Lẹẹkeji ohùn náà tún wá láti ọ̀run. Ó ní, ‘Ohunkohun tí Ọlọrun bá ti sọ di mímọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ pè é ní aláìmọ́ mọ́.’ +Peteru Ròyìn fún Ìjọ ní Jerusalẹmu. +Ní àkókò náà Hẹrọdu ọba bẹ̀rẹ̀ sí ṣe inúnibíni sí àwọn kan ninu ìjọ. +Wọ́n kọjá ẹ̀ṣọ́ kinni ati ekeji, wọ́n wá dé ẹnu ọ̀nà ńlá onírin tí ó jáde sinu ìlú. Fúnra ìlẹ̀kùn yìí ni ó ṣí sílẹ̀ fún wọn. Wọ́n bá jáde sí ojú ọ̀nà kan. Lójú kan náà, angẹli bá rá mọ́ Peteru lójú. +Ojú Peteru wá wálẹ̀. Ó ní, “Mo wá mọ̀ nítòótọ́ pé Oluwa ni ó rán angẹli rẹ̀ láti gbà mí lọ́wọ́ Hẹrọdu, ati láti yọ mí kúrò ninu ohun gbogbo tí àwọn Juu ti ń retí.” +Nígbà tí ó rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Maku. Ọpọlọpọ eniyan ni ó péjọ sibẹ tí wọn ń gbadura. +Nígbà tí Peteru kan ìlẹ̀kùn tí ó wà lójúde, ọdọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Roda wá láti ṣí i. +Nígbà tí ó gbọ́ ohùn Peteru, inú rẹ̀ dùn tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi dúró ṣí ìlẹ̀kùn; ṣugbọn ó sáré lọ sinu ilé, ó lọ sọ pé Peteru wà lóde lẹ́nu ọ̀nà. +Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bú u pé, “Orí rẹ dàrú!” Ṣugbọn ó ṣá tẹnumọ́ ọn pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí. Wọ́n wá sọ pé, “A jẹ́ pé angẹli rẹ̀ ni!” +Ṣugbọn Peteru tún ń kanlẹ̀kùn. Nígbà tí wọ́n ṣí i, tí wọ́n rí i, ẹnu yà wọ́n. +Ó bá fi ọwọ́ ṣe àmì sí wọn kí wọ́n dákẹ́; ó ròyìn fún wọn bí Oluwa ti ṣe mú òun jáde kúrò lẹ́wọ̀n. Ó ní kí wọn ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jakọbu ati fún àwọn arakunrin yòókù. Ó bá jáde, ó lọ sí ibòmíràn. +Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ìdààmú ńlá bá àwọn ọmọ-ogun. Wọn kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Peteru. +Hẹrọdu wá Peteru títí, ṣugbọn kò rí i. Lẹ́yìn tí ó ti wádìí lẹ́nu àwọn ẹ̀ṣọ́ tán, ó ní kí wọ́n pa wọ́n.Ni Hẹrọdu bá kúrò ní Judia, ó lọ sí Kesaria, ó lọ gbé ibẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. +Ó bẹ́ Jakọbu arakunrin Johanu lórí. +Inú bí Hẹrọdu pupọ sí àwọn ará Tire ati Sidoni. Àwọn ará ìlú wọnyi bá fi ohùn ṣọ̀kan, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n tu Bilasitu tíí ṣe ìjòyè ọba tí ó ń mójútó ààfin lójú, wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ pé kí ọba má bínú sí àwọn nítorí láti ilé ọba ni wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ. +Nígbà tí ó di ọjọ́ tí ọba dá fún wọn, Hẹrọdu yọ dé pẹlu aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó wá bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀. +Ni àwọn eniyan náà bá ń kígbe pé, “Ohùn Ọlọrun nìyí, kì í ṣe ti eniyan!” +Lẹsẹkẹsẹ angẹli Oluwa bá lù ú pa, nítorí kò fi ògo fún Ọlọrun. Ni ìdin bá jẹ ẹ́ pa. +Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bẹ̀rẹ̀ sí fìdí múlẹ̀ sí i, ó sì túbọ̀ ń tàn káàkiri. +Nígbà tí Banaba ati Saulu parí iṣẹ́ tí a rán wọn, wọ́n pada láti Jerusalẹmu, wọ́n mú Johanu tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Maku lọ́wọ́. +Nígbà tí ó rí i pé ó dùn mọ́ àwọn Juu, ó bá tún mú Peteru náà. Àkókò náà ni Àjọ̀dún Àìwúkàrà. +Ó bá mú Peteru ó tì í mọ́lé. Ó fi í lé àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun mẹrin lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ; (ọmọ-ogun mẹrin ni ó wà ní ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan). Hẹrọdu fẹ́ mú Peteru wá siwaju gbogbo eniyan fún ìdájọ́ lẹ́yìn Àjọ̀dún Ìrékọjá. +Wọ́n bá sọ Peteru sẹ́wọ̀n, ṣugbọn gbogbo ìjọ ń fi tọkàntọkàn gbadura sí Ọlọrun nítorí rẹ̀. +Ní òru, mọ́jú ọjọ́ tí Hẹrọdu ìbá mú Peteru wá fún ìdájọ́, Peteru sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun meji, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é; àwọn ọmọ-ogun kan sì tún wà lẹ́nu ọ̀nà, tí wọn ń ṣọ́nà. +Angẹli Oluwa kan bá yọ dé, ìmọ́lẹ̀ sì tàn ninu ilé náà. Angẹli náà bá rọra lu Peteru lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ní, “Dìde kíá.” Àwọn ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi de Peteru bá yọ bọ́ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, +Angẹli náà sọ fún un pé, “Di ìgbànú rẹ, sì wọ sálúbàtà rẹ.” Peteru bá ṣe bí angẹli náà ti wí. Angẹli yìí tún sọ fún un pé, “Da aṣọ rẹ bora, kí o máa tẹ̀lé mi.” +Ni Peteru bá tẹ̀lé e jáde. Kò mọ̀ pé òtítọ́ ni ohun tí ó ti ọwọ́ angẹli náà ṣẹlẹ̀, ó ṣebí àlá ni. +Inúnibíni sí ìjọ. +Àwọn wolii ati àwọn olùkọ́ wà ninu ìjọ tí ó wà ní Antioku. Ninu wọn ni Banaba ati Simeoni tí wọn ń pè ní Adúláwọ̀ wà, ati Lukiusi ará Kirene, ati Manaeni tí wọ́n jọ tọ́ dàgbà pẹlu Hẹrọdu baálẹ̀, ati Saulu. +ó ní, “Ìwọ yìí, tí ó jẹ́ kìkì oríṣìíríṣìí ẹ̀tàn ati ìwà burúkú! Ìwọ ọmọ èṣù yìí! Ọ̀tá gbogbo nǹkan tí ó dára! O kò ní yé yí ọ̀nà títọ́ Oluwa po! +Ọwọ́ Oluwa tẹ̀ ọ́ nisinsinyii. Ojú rẹ yóo fọ́, o kò ní lè rí oòrùn fún ìgbà kan!”Lójú kan náà, ìkùukùu dúdú dà bò ó. Ó bá ń tá ràrà, ó ń wá ẹni tí yóo fà á lọ́wọ́ kiri. +Nígbà tí gomina rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó gbàgbọ́; nítorí pé ẹ̀kọ́ nípa Oluwa yà á lẹ́nu. +Nígbà tí Paulu ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kúrò ní Pafọsi, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí ìlú Pega ní ilẹ̀ Pamfilia. Johanu fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀, ó pada lọ sí Jerusalẹmu. +Wọ́n la ilẹ̀ náà kọjá láti Pega títí wọ́n fi dé ìlú Antioku lẹ́bàá ilẹ̀ Pisidia. Wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu ní Ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n bá jókòó. +Lẹ́yìn tí wọ́n ti ka Ìwé Mímọ́, láti inú Ìwé Òfin Mose ati Ìwé àwọn wolii, àwọn olóyè ilé ìpàdé àwọn Juu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin arakunrin, bí ẹ bá ní ọ̀rọ̀ ìyànjú fún àwọn eniyan, ẹ sọ ọ́.” +Ni Paulu bá dìde, ó gbé ọwọ́ sókè, ó ní:“Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sin Ọlọrun wa, ẹ fetí sílẹ̀. +Ọlọrun àwọn eniyan yìí, eniyan Israẹli, yan àwọn baba wa. Nígbà tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti bí àlejò, Ọlọrun sọ wọ́n di eniyan ńlá. Ó fi agbára ńlá rẹ̀ hàn nígbà tí ó mú wọn jáde kúrò ní Ijipti. +Fún nǹkan bí ogoji ọdún ni ó fi ń kẹ́ wọn ní aṣálẹ̀. +Orílẹ̀-èdè meje ni ó parẹ́ ní ilẹ̀ Kenaani nítorí tiwọn, ó sì jẹ́ kí wọ́n jogún ilẹ̀ wọn, +Bí wọ́n ti jọ ń sin Oluwa, tí wọ́n ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sọ fún wọn pé, “Ẹ ya Banaba ati Saulu sọ́tọ̀ fún mi, fún iṣẹ́ pataki kan tí mo ti pè wọ́n fún.” +fún nǹkan bí irinwo ọdún ó lé aadọta (450). “Lẹ́yìn èyí ó fún wọn ní àwọn onídàájọ́ títí di àkókò wolii Samuẹli. +Lẹ́yìn náà wọ́n bèèrè fún ọba; Ọlọrun bá fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ó jọba fún ogoji ọdún. +Nígbà tí Ọlọrun yọ ọ́ lóyè, ó gbé Dafidi dìde fún wọn bí ọba. Ọlọrun jẹ́rìí sí ìwà rẹ̀ nígbà tí ó sọ pé, ‘Mo rí i pé Dafidi ọmọ Jese jẹ́ ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́, ẹni tí yóo ṣe ohun gbogbo bí mo ti fẹ́.’ +Láti inú ìran rẹ̀ ni Ọlọrun ti gbé Jesu dìde bí Olùgbàlà fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí. +Kí Jesu tó yọjú, Johanu ti ń waasu fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi bí àmì pé wọ́n ronupiwada. +Nígbà tí Johanu fẹ́rẹ̀ dópin iṣẹ́ rẹ̀, ó ní, ‘Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́? Èmi kì í ṣe ẹni tí ẹ rò. Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí n kò tó tú okùn bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀.’ +“Ẹ̀yin arakunrin, ìran Abrahamu, ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sin Ọlọrun, àwa ni a rán iṣẹ́ ìgbàlà yìí sí. +Àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn olóyè wọn, wọn kò mọ ẹni tí Jesu jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí àwọn wolii ń sọ kò yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń kà á. Wọ́n mú àkọsílẹ̀ wọnyi ṣẹ nígbà tí wọ́n dá a lẹ́bi ikú. +Láìjẹ́ pé wọ́n rí ohunkohun tí ó fi jẹ̀bi ikú, wọ́n ní kí Pilatu pa á. +Nígbà tí wọ́n ti parí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé yóo ṣẹlẹ̀ sí i, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí igi agbelebu, wọ́n tẹ́ ẹ sinu ibojì. +Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbààwẹ̀, tí wọ́n sì gbadura, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn lórí, wọ́n sì ní kí wọ́n máa lọ. +Ṣugbọn Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú. +Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni ó fi ara hàn fún àwọn tí wọ́n bá a wá sí Jerusalẹmu láti Galili. Àwọn ni ẹlẹ́rìí fún gbogbo eniyan pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí. +A wá mú ìyìn rere wá fun yín pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa ti ṣẹ, fún àwọn ọmọ wa, nígbà tí ó jí Jesu dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Orin Dafidi keji pé,‘Ọmọ mi ni ọ́, lónìí yìí ni mo bí ọ.’ +Ní ti pé ó jí i dìde kúrò ninu òkú, tí kò pada sí ipò ìdíbàjẹ́ mọ́, ohun tí ó sọ ni pé, ‘Èmi yóo fun yín ní ohun tí mo bá Dafidi pinnu.’ +Bẹ́ẹ̀ ni ó tún sọ níbòmíràn pé, ‘O kò ní jẹ́ kí Ẹni ọ̀wọ̀ rẹ mọ ìdíbàjẹ́.’ +Nítorí nígbà tí Dafidi ti sin ìran tirẹ̀ tán gẹ́gẹ́ bí ète Ọlọrun, ó sun oorun ikú, ó lọ bá àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ rà nílẹ̀. +Ṣugbọn ẹni tí Ọlọrun jí dìde kò ní ìrírí ìdíbàjẹ́. +Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kí ó hàn si yín pé nítorí ẹni yìí ni a ṣe ń waasu ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fun yín. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹni yì�� ni a fi dá gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ láre, àwọn tí Òfin Mose kò lè dá láre. +Lẹ́yìn tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti fi iṣẹ́ lé àwọn mejeeji lọ́wọ́, wọ́n lọ sí Selesia. Láti ibẹ̀ wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kipru. +Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ohun tí a kọ sílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii má baà dé ba yín: +‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ó yà yín lẹ́nu, kí ẹ sì parun! Nítorí n óo ṣe iṣẹ́ kan ní àkókò yín,tí ẹ kò ní gbàgbọ́ bí ẹnìkan bá ròyìn rẹ̀ fun yín.’ ” +Bí Paulu ati Banaba ti ń jáde lọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan ń bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n tún pada wá bá wọn sọ irú ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀sẹ̀ tí ó ń bọ̀. +Nígbà tí ìpàdé túká, ọpọlọpọ àwọn Juu ati àwọn tí wọ́n ti di ẹlẹ́sìn àwọn Juu ń tẹ̀lé Paulu ati Banaba. Àwọn òjíṣẹ́ mejeeji yìí tún ń bá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n dúró láì yẹsẹ̀ ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. +Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi keji, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìlú ni ó péjọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa. +Nígbà tí àwọn Juu rí ọ̀pọ̀ eniyan, owú mú kí inú bí wọn. Wọ́n bá ń bu ẹnu àtẹ́ lu ohun tí Paulu ń sọ; wọ́n ń sọ ìsọkúsọ sí wọn. +Paulu ati Banaba wá fi ìgboyà sọ pé, “Ẹ̀yin ni a níláti kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún. Ṣugbọn nígbà tí ẹ kọ̀ ọ́, tí ẹ kò ka ara yín yẹ fún ìyè ainipẹkun, àwa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Juu. +Nítorí bẹ́ẹ̀ ni Oluwa pa láṣẹ fún wa nígbà tí ó sọ pé: ‘Mo ti fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù,kí ìgbàlà mi lè dé òpin ilẹ̀ ayé.’ ” +Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu gbọ́, inú wọn dùn. Wọ́n dúpẹ́ fún ọ̀rọ̀ Oluwa. Gbogbo àwọn tí a ti yàn láti ní ìyè ainipẹkun bá gbàgbọ́. +Ọ̀rọ̀ Oluwa tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà. +Nígbà tí wọ́n dé Salami, wọ́n waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ninu àwọn ilé ìpàdé àwọn Juu. Wọ́n mú Johanu lọ́wọ́ kí wọn lè máa rí i rán níṣẹ́. +Ṣugbọn àwọn Juu rú àwọn gbajúmọ̀ obinrin olùfọkànsìn sókè, ati àwọn eniyan pataki-pataki ní ìlú, ni wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí Paulu ati Banaba. Wọ́n lé wọn jáde kúrò ní agbègbè wọn. +Ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sílẹ̀ bí ẹ̀rí sí àwọn ará ìlú náà, wọ́n bá lọ sí Ikoniomu. +Ayọ̀ kún ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sì kún inú wọn. +Wọ́n la erékùṣù náà kọjá, wọ́n dé Pafọsi. Níbẹ̀ ni wọ́n rí ọkunrin Juu kan, tí ó ń pidán, tí ó fi ń tú àwọn eniyan jẹ. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ba-Jesu. +Ọkunrin yìí ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ gomina ilẹ̀ náà, tí ń jẹ́ Segiu Paulu. Gomina yìí jẹ́ olóye eniyan. Ó ranṣẹ pe Banaba ati Saulu nítorí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. +Ṣugbọn Elimasi, tí ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ jẹ́ onídán, takò wọ́n. Ó ń wá ọ̀nà láti yí ọkàn gomina pada kúrò ninu igbagbọ. +Ẹ̀mí Mímọ́ bá gbé Saulu, tí a tún ń pè ní Paulu. Ó tẹjú mọ́ onídán náà, +A Yan Banaba ati Saulu fún Iṣẹ́ Pataki. +Nígbà tí wọ́n dé Ikoniomu, wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. Wọ́n sọ̀rọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọpọlọpọ ninu àwọn Juu ati àwọn Giriki fi gba Jesu gbọ́. +Ó bá kígbe sókè, ó ní, “Dìde, kí o dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ bí eniyan.” Ni ọkunrin arọ náà bá fò sókè, ó bá ń rìn. +Nígbà tí àwọn eniyan rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n kígbe ní èdè Likaonia pé, “Àwọn oriṣa ti di eniyan, wọ́n tọ̀run wá sáàrin wa!” +Wọ́n pe Banaba ní Seusi, wọ́n pe Paulu ní Herime nítorí òun ni ó ń ṣe ògbifọ̀. +Ní òde kí á tó wọ odi ìlú ni tẹmpili Seusi wà. Baba olórìṣà Seusi bá mú mààlúù ati òdòdó jìngbìnnì, òun ati ọpọlọpọ èrò, wọ́n ń bọ̀ lẹ́nu odi ìlú níbi tí pẹpẹ Seusi wà, wọ́n fẹ́ wá bọ wọ́n. +Nígbà tí Banaba aposteli ati Paulu aposteli gbọ́, wọ́n fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n bá pa kuuru mọ́ àwọn èrò, wọ́n ń kígbe pé, +“Ẹ̀yin eniyan, kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe irú eléyìí? Eniyan bíi yín ni àwa náà. À ń waasu fun yín pé kí ẹ yipada kúrò ninu àwọn ohun asán wọnyi, kí ẹ sin Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, ati òkun ati ohun gbogbo tí ó wà ninu wọn. +Ní ìgbà ayé àwọn tí ó ti kọjá, ó jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n. +Sibẹ kò ṣàì fi àmì ara rẹ̀ hàn: ó ń ṣe iṣẹ́ rere, ó ń rọ òjò fun yín láti ọ̀run, ó ń mú èso jáde lásìkò, ó ń fun yín ní oúnjẹ, ó tún ń mú inú yín dùn.” +Pẹlu gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, agbára-káká ni wọn kò fi jẹ́ kí àwọn eniyan bọ wọ́n. +Ṣugbọn àwọn Juu dé láti Antioku ati Ikoniomu, wọ́n yí ọkàn àwọn eniyan pada, wọ́n sọ Paulu ní òkúta, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sẹ́yìn odi, wọ́n ṣebí ó ti kú. +Àwọn Juu tí kò gbà pé Jesu ni Mesaya wá gbin èrò burúkú sí ọkàn àwọn tí kì í ṣe Juu, wọ́n rú wọn sókè sí àwọn onigbagbọ. +Ṣugbọn àwọn onigbagbọ pagbo yí i ká títí ó fi dìde tí ó sì wọ inú ìlú lọ. Ní ọjọ́ keji ó gbéra lọ sí Dabe pẹlu Banaba. +Wọ́n waasu ìyìn rere ní ìlú náà, àwọn eniyan pupọ sì di onigbagbọ. Wọ́n bá pada sí Listira ati Ikoniomu ati Antioku ní Pisidia. +Wọ́n ń mú àwọn onigbagbọ lọ́kàn le pé kí wọ́n dúró ṣinṣin ninu igbagbọ. Wọ́n ń fi yé wọn pé kí eniyan tó wọ ìjọba Ọlọrun, ó níláti ní ọpọlọpọ ìṣòro. +Wọ́n yan àgbà ìjọ fún wọn ninu ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí wọ́n ti gbadura, tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, wọ́n fi wọ́n lé ọwọ́ Oluwa tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé. +Wọ́n wá gba Pisidia kọjá lọ sí Pamfilia. +Nígbà tí wọ́n ti waasu ìyìn rere ní Pega, wọ́n lọ sébùúté ní Atalia. +Wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi láti ibẹ̀ lọ sí Antioku ní Siria níbi tí wọ́n ti kọ́ fi wọ́n sábẹ́ ojurere Ọlọrun fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ parí. +Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n pe gbogbo ìjọ jọ, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọrun tọwọ́ wọn ṣe ati bí Ọlọrun ti ṣínà fún àwọn tí kì í ṣe Juu láti gbàgbọ́. +Wọ́n dúró níbẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onigbagbọ fún ìgbà pípẹ́. +Paulu ati Banaba pẹ́ níbẹ̀. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, ẹ̀rù kò sì bà wọ́n nítorí wọ́n gbójú lé Oluwa tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ti ọwọ́ wọn ṣe. +Ìyapa bẹ́ sáàrin àwọn eniyan ninu ìlú; àwọn mìíràn fara mọ́ àwọn Juu, àwọn mìíràn fara mọ́ àwọn aposteli. +Àwọn Juu ati àwọn tí kì í ṣe Juu pẹlu àwọn ìjòyè wọn dábàá láti ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́, wọ́n fẹ́ sọ wọ́n ní òkúta pa. +Nígbà tí àwọn aposteli mọ̀, wọ́n sálọ sí Listira ati Dabe, ìlú meji ní Likaonia, ati àwọn agbègbè wọn. +Wọ́n bá ń waasu ìyìn rere níbẹ̀. +Ọkunrin kan wà ní ìjókòó ní Listira tí ó yarọ. Láti ìgbà tí wọ́n ti bí i ni ó ti yarọ, kò fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn rí. +Ọkunrin yìí fetí sílẹ̀ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀. Paulu wá tẹjú mọ́ ọn lára, ó rí i pé ó ní igbagbọ pé wọ́n lè mú òun lára dá. +Iṣẹ́ Paulu ati Banaba ní Ikoniomu. +Àwọn kan wá láti Judia tí wọn ń kọ́ àwọn onigbagbọ pé, “Bí ẹ kò bá kọlà gẹ́gẹ́ bí àṣà ati Òfin Mose, a kò lè gbà yín là!” +Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ní ṣe tí ẹ fi fẹ́ dán Ọlọrun wò, tí ẹ fẹ́ gbé àjàgà tí àwọn baba wa ati àwa náà kò tó rù, rù àwọn ọmọ-ẹ̀yìn? +A gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Jesu Oluwa ni a fi gbà wá là, gẹ́gẹ́ bí a ti fi gba àwọn náà là.” +Ńṣe ni gbogbo àwùjọ dákẹ́ jẹ́ẹ́. Wọ́n wá fetí sílẹ̀ sí ohun tí Banaba ati Paulu níí sọ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọrun tọwọ́ wọn ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. +Lẹ́yìn tí wọ́n ti parí ọ̀rọ̀ tí wọ́n níí sọ, Jakọbu bá fèsì pé, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ fetí sí mi. +Simoni ti ròyìn ọ̀nà tí Ọlọrun kọ́kọ́ fi ṣe ìkẹ́ àwọn tí kì í ṣe Juu kí ó lè mú ninu wọn fi ṣe eniyan tirẹ̀. +Ọ̀rọ̀ àwọn wolii bá èyí mu, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, +‘Lẹ́yìn èyí, n óo tún ilé Dafidi tí ó ti wó kọ́. N óo tún ahoro rẹ̀ mọ,n óo sì gbé e ró. +Báyìí ni gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo máa wá Oluwa,ati gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo ti pè láti jẹ́ tèmi. +Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí,ó sì jẹ́ kí á mọ ọ̀rọ̀ náà láti ìgbà àtijọ́-tijọ́.’ +“Ní tèmi, èrò mi ni pé kí á má tún yọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n yipada sí Ọlọrun lẹ́nu mọ́. +Ó di ọ̀rọ̀ líle ati àríyànjiyàn ńlá láàrin àwọn ati Paulu ati Banaba. Ni ìjọ bá pinnu pé kí Paulu ati Banaba ati àwọn mìíràn láàrin wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli ati àwọn alàgbà ní Jerusalẹmu láti yanjú ọ̀rọ̀ náà. +Kàkà bẹ́ẹ̀ kí á kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n takété sí ohunkohun tí ó bá ti di àìmọ́ nítorí pé a ti fi rúbọ sí oriṣa; kí wọn má ṣe àgbèrè, kí wọn má jẹ ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa, kí wọn má sì jẹ ẹ̀jẹ̀. +Nítorí láti ìgbà àtijọ́ ni wọ́n ti ń ké òkìkí Mose láti ìlú dé ìlú tí wọn sì ń ka ìwé rẹ̀ ninu gbogbo ilé ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.” +Àwọn aposteli ati àwọn àgbà ìjọ pẹlu gbogbo ìjọ wá pinnu láti yan àwọn eniyan láàrin wọn, láti rán lọ sí Antioku pẹlu Paulu ati Banaba. Wọ́n bá yan Juda tí à ń pè ní Basaba ati Sila, tí wọn jẹ́ aṣaaju láàrin àwọn onigbagbọ. +Wọ́n fi ìwé rán wọn, pé:“Àwa aposteli ati àwa alàgbà kí ẹ̀yin tí kì í ṣe Juu ní Antioku, Siria ati Silisia; a kí yín bí arakunrin sí arakunrin. +A gbọ́ pé àwọn kan láti ọ̀dọ̀ wa ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, wọn kò jẹ́ kí ọkàn yín balẹ̀. A kò rán wọn níṣẹ́. +A ti wá pinnu, gbogbo wa sì fohùn sí i, a wá yan àwọn eniyan láti rán si yín pẹlu Banaba ati Paulu, àwọn àyànfẹ́ wa, +àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ nítorí orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi. +Nítorí náà a rán Juda ati Sila, láti fẹnu sọ ohun kan náà tí a kọ sinu ìwé fun yín. +Ẹ̀mí Mímọ́ ati àwa náà pinnu pé kí á má tún di ẹrù tí ó wúwo jù le yín lórí mọ́, yàtọ̀ sí àwọn nǹkan pataki wọnyi: +kí ẹ má jẹ ẹran tí a fi rúbọ sí oriṣa; kí ẹ má jẹ ẹ̀jẹ̀; kí ẹ má jẹ ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí ẹ má ṣe àgbèrè. Bí ẹ bá takété sí àwọn nǹkan wọnyi, yóo dára. Ó dìgbà o!” +Àwọn ìjọ sìn wọ́n sọ́nà, wọ́n wá gba Fonike ati Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ń yipada di onigbagbọ. Èyí mú kí inú gbogbo àwọn onigbagbọ tí wọ́n gbọ́ dùn pupọ. +Nígbà tí àwọn tí a rán kúrò, wọ́n dé Antioku, wọ́n pe gbogbo ìjọ, wọ́n fún wọn ní ìwé náà. +Nígbà tí wọ́n kà á, inú wọn dùn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó wà ninu rẹ̀. +Juda ati Sila, tí wọ́n jẹ́ wolii fúnra wọn, tún fi ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ gba ẹgbẹ́ onigbagbọ náà níyànjú, wọ́n tún mú wọn lọ́kàn le. +Wọ́n dúró fún ìgbà díẹ̀, ni àwọn ìjọ bá fi tayọ̀tayọ̀ rán wọn pada lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá. [ +Ṣugbọn Sila pinnu láti dúró níbẹ̀.] +Ṣugbọn Paulu ati Banaba dúró ní Antioku, wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn ati eniyan pupọ mìíràn ń waasu ọ̀rọ̀ Oluwa. +Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ Paulu wí fún Banaba pé, “Jẹ́ kí á pada lọ bẹ àwọn onigbagbọ wò ní gbogbo ìlú tí a ti waasu ọ̀rọ̀ Oluwa, kí a rí bí wọ́n ti ń ṣe.” +Banaba fẹ́ mú Johanu tí à ń pè ní Maku lọ. +Ṣugbọn Paulu kò rò pé ó yẹ láti mú un lọ, nítorí ó pada lẹ́yìn wọn ní Pamfilia, kò bá wọn lọ títí dé òpin iṣẹ́ náà. +Àríyànjiyàn náà le tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi pínyà, tí olukuluku fi bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Banaba mú Maku, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kipru. +Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, gbogbo ìjọ, ati àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà gbà wọ́n tọwọ́-tẹsẹ̀. Wọ́n wá ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọrun ti ṣe fún wọ́n. +Paulu mú Sila ó bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ lẹ́yìn tí àwọn onigbagbọ ti fi í lé oore-ọ̀fẹ́ Oluwa lọ́wọ́. +Ó gba Siria ati Silisia kọjá, ó ń mú àwọn ìjọ lọ́kàn le. +Àwọn kan láti inú ẹgbẹ́ àwọn Farisi tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ wá dìde. Wọ́n ní, “Dandan ni pé kí á kọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí ó bá fẹ́ di onigbagbọ nílà, kí á sì pàṣẹ fún wọn láti máa pa Òfin Mose mọ́.” +Gbogbo àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà bá péjọ láti rí sí ọ̀rọ̀ yìí. +Àríyànjiyàn pupọ ni ó bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn. Peteru bá dìde, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ̀yin gan-an mọ̀ pé ní àtijọ́ Ọlọrun yàn mí láàrin yín pé láti ẹnu mi ni àwọn tí kì í ṣe Juu yóo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere, kí wọ́n lè gba Jesu gbọ́. +Ọlọrun olùmọ̀ràn ọkàn fún wọn ní ìwé ẹ̀rí nígbà tí ó fún wọn ní Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti fún wa. +Kò fi ìyàtọ̀ kankan sáàrin àwa ati àwọn; ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nítorí wọ́n gba Jesu gbọ́. +Ìgbìmọ̀ Ìjọ Jerusalẹmu. +Paulu dé Dabe ati Listira. Onigbagbọ kan tí ń jẹ́ Timoti wà níbẹ̀. Ìyá rẹ̀ jẹ́ Juu tí ó gba Jesu gbọ́; ṣugbọn Giriki ni baba rẹ̀. +Gbàrà tí ó rí ìran náà, a wá ọ̀nà láti lọ sí Masedonia; a pinnu pé Ọlọrun ni ó pè wá láti lọ waasu fún wọn níbẹ̀. +Nígbà tí a wọ ọkọ̀ láti Tiroasi, a lọ tààrà sí Samotirake. Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Neapoli. +Láti ibẹ̀, a lọ sí Filipi tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ Masedonia. Àwọn ará Romu ni wọ́n tẹ ìlú yìí dó. A bá wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan. +Ní Ọjọ́ Ìsinmi a jáde lọ sẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá odò, níbi tí a rò pé a óo ti rí ibi tí wọn máa ń gbadura. A bá jókòó, a bá àwọn obinrin tí ó péjọ níbẹ̀ sọ̀rọ̀. +Obinrin kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ́ Lidia, ará Tiatira, tí ó ń ta aṣọ àlàárì. Ó jẹ́ ẹnìkan tí ó ń sin Ọlọrun. Ó fetí sílẹ̀, Ọlọrun ṣí i lọ́kàn láti gba ohun tí Paulu ń sọ. +Òun ati àwọn ará ilé rẹ̀ gba ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀ wá pé, bí a bá gbà pé òun jẹ́ onigbagbọ nítòótọ́, kí á máa bọ̀ ní ilé òun kí á máa bá àwọn gbé. Ó tẹnu mọ́ ọn títí a fi gbà. +Ní ọjọ́ kan, bí a ti ń lọ sí ibi adura, a pàdé ọdọmọbinrin kan tí ó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ. Ó ti ń mú èrè pupọ wá fún àwọn olówó rẹ̀ nípa àfọ̀ṣẹ rẹ̀. +Ó ń tẹ̀lé Paulu ati àwa náà, ó ń kígbe pé, “Àwọn ọkunrin yìí ni iranṣẹ Ọlọrun Ọ̀gá Ògo; àwọn ni wọ́n ń waasu ọ̀nà ìgbàlà fun yín.” +Ó ń ṣe báyìí fún ọjọ́ pupọ. Nígbà tí ara Paulu kò gbà á mọ́, ó yipada, ó sọ fún ẹ̀mí náà pé, “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jesu, jáde kúrò ninu rẹ̀.” Ni ó bá jáde lẹ́sẹ̀ kan náà. +Nígbà tí àwọn olówó ọdọmọbinrin náà rí i pé ọ̀nà oúnjẹ wọ́n ti dí, wọ́n ki Paulu ati Sila mọ́lẹ̀, wọ́n fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ní ọjà. +Àwọn arakunrin ní Listira ati Ikoniomu ròyìn Timoti yìí dáradára. +Wọ́n mú wọn wá siwaju àwọn adájọ́. Wọ́n ní, “Juu ni àwọn ọkunrin wọnyi, wọ́n sì ń da ìlú wa rú. +Wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan ní àṣà tí kò tọ́ fún wa láti gbà tabi láti ṣe nítorí ará Romu ni wá.” +Ni àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí lu Paulu ati Sila.Àwọn adájọ́ fa aṣọ ya mọ́ wọn lára, wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n nà wọ́n. +Nígbà tí wọ́n ti nà wọ́n dáradára, wọ́n bá sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. Wọ́n pàṣẹ fún ẹni tí ó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí ó ṣọ́ wọn dáradára. +Nígbà tí ó ti gba irú àṣẹ báyìí, ó sọ wọ́n sinu àtìmọ́lé ti inú patapata, ó tún fi ààbà kan ẹsẹ̀ wọn mọ́ igi. +Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, Paulu ati Sila ń gbadura, wọ́n ń kọrin sí Ọlọrun. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù ń dẹtí sí wọn. +Lójijì ni ilẹ̀ mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé ẹ̀wọ̀n mì. Lọ́gán gbogbo ìlẹ̀kùn ṣí; gbogbo ẹ̀wọ̀n tí a fi de àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì tú. +Nígbà tí ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n jí lójú oorun, tí ó rí i pé ìlẹ̀kùn ilé ẹ̀wọ̀n ti ṣí, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣebí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sálọ ni. +Paulu bá kígbe pè é, ó ní, “Má ṣe ara rẹ léṣe, nítorí gbogbo wa wà níhìn-ín.” +Ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá bèèrè iná, ó pa kuuru wọ inú iyàrá, ó ń gbọ̀n láti orí dé ẹsẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Paulu ati Sila. +Òun ni ó wu Paulu láti mú lọ sí ìrìn-àjò rẹ̀, nítorí náà, ó mú un, ó kọ ọ́ nílà nítorí àwọn Juu tí ó wà ní agbègbè ibẹ̀; nítorí gbogbo wọn ni wọ́n mọ̀ pé Giriki ni baba rẹ̀. +Ó mú wọn jáde, ó ní, “Ẹ̀yin alàgbà, kí ni ó yẹ kí n ṣe kí n lè là?” +Wọ́n dá a lóhùn pé, “Gba Jesu Oluwa gbọ́, ìwọ ati ìdílé rẹ yóo sì là.” +Wọ́n bá sọ ọ̀rọ̀ Oluwa fún òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀. +Ní òru náà, ó mú wọn, ó wẹ ọgbẹ́ wọn. Lójú kan náà òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì ṣe ìrìbọmi. +Ó bá mú wọn wọ ilé, ó fún wọn ní oúnjẹ. Inú òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ dùn pupọ nítorí ó ti gba Ọlọrun gbọ́. +Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn adájọ́ rán àwọn iranṣẹ sí ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n pé, kí ó dá àwọn eniyan náà sílẹ̀. +Ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá lọ jíṣẹ́ fún Paulu pé, “Àwọn adájọ́ ti ranṣẹ pé kí á da yín sílẹ̀. Ẹ jáde kí ẹ máa lọ ní alaafia.” +Ṣugbọn Paulu sọ fún wọn pé, “Wọ́n nà wá ní gbangba láì ká ẹ̀bi mọ́ wa lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni wá. Wọ́n sọ wá sẹ́wọ̀n, wọ́n wá fẹ́ tì wá jáde níkọ̀kọ̀. Rárá o! Kí àwọn fúnra wọn wá kó wa jáde.” +Àwọn iranṣẹ tí àwọn adájọ́ rán wá lọ ròyìn ọ̀rọ̀ wọnyi fún wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni wọ́n jẹ́. +Wọ́n bá wá, wọ́n bẹ̀ wọ́n. Wọ́n sìn wọ́n jáde, wọ́n bá rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kúrò ninu ìlú. +Bí wọ́n ti ń lọ láti ìlú dé ìlú, wọ́n ń sọ fún wọn nípa ìpinnu tí àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà ní Jerusalẹmu ṣe, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n pa wọ́n mọ́. +Nígbà tí wọ́n jáde kúrò lẹ́wọ̀n, wọ́n lọ sí ilé Lidia. Lẹ́yìn tí wọ́n rí àwọn onigbagbọ, tí wọ́n sì gbà wọ́n níyànjú, wọ́n kúrò níbẹ̀. +Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ túbọ̀ ń lágbára sí i ninu igbagbọ, tí wọ́n sì ń pọ̀ sí i ní iye lojoojumọ. +Wọ́n gba ilẹ̀ Firigia ati Galatia kọjá. Ẹ̀mí Mímọ́ kò gbà wọ́n láàyè láti lọ waasu ọ̀r��̣ Oluwa ní Esia. +Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Misia, wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bitinia. Ṣugbọn Ẹ̀mí Jesu kò gbà fún wọn. +Nígbà tí wọ́n ti la Misia kọjá, wọ́n dé Tiroasi. +Nígbà tí ó di alẹ́, Paulu rí ìran kan. Ó rí ọkunrin kan ará Masedonia tí ó dúró, tí ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Sọdá sí Masedonia níbí kí o wá ràn wá lọ́wọ́.” +Timoti ba Paulu ati Sila lọ. +Wọ́n kọjá ní Amfipoli ati Apolonia kí wọn tó dé Tẹsalonika. Ilé ìpàdé àwọn Juu kan wà níbẹ̀. +Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn onigbagbọ tètè ṣe ètò láti mú Paulu ati Sila lọ sí Beria. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu. +Àwọn yìí ṣe onínú rere ju àwọn Juu ti Tẹsalonika lọ. Wọ́n fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Lojoojumọ ni wọ́n ń wá inú Ìwé Mímọ́ wò láti rí bí àwọn ohun tí wọ́n kọ́ wọn rí bẹ́ẹ̀. +Pupọ ninu wọn gbàgbọ́, ati pupọ ninu àwọn Giriki tí wọ́n jẹ́ eniyan pataki-pataki, lọkunrin ati lobinrin. +Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu ní Tẹsalonika mọ̀ pé Paulu ti tún waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní Beria, wọ́n wá sibẹ láti ṣe màdàrú ati láti dá rúkèrúdò sílẹ̀. +Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn onigbagbọ bá ṣe ètò fún Paulu láti lọ sí èbúté. Ṣugbọn Sila ati Timoti dúró ní Beria. +Àwọn tí ó sin Paulu lọ mú un dé Atẹni. Wọ́n wá gba ìwé pada fún Sila ati Timoti pé kí wọ́n tètè wá bá a. +Nígbà tí Paulu ń dúró dè wọ́n ní Atẹni, ó rí ìlú náà bí ó ti kún fún ère oriṣa. Eléyìí sì dùn ún dọ́kàn. +Nítorí náà, ó ń bá àwọn Juu ati àwọn olùfọkànsìn tí kì í ṣe Juu jiyàn ninu ilé ìpàdé ní ojoojumọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ń ṣe láàrin ọjà, ó ń bá ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nítòsí sọ̀rọ̀. +Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan ninu àwọn ọmọlẹ́yìn Epikurusi ati àwọn Sitoiki bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Kí ni aláhesọ yìí ń wí?”Àwọn mìíràn ní, “Ó jọ pé òjíṣẹ́ oriṣa àjèjì kan ni!” Nítorí ó ń waasu nípa Jesu ati ajinde. +Ni wọ́n bá ní kí ó kálọ sí Òkè Areopagu. Wọ́n wá bi í pé, “Ǹjẹ́ a lè mọ ohun tí ẹ̀kọ́ titun tí ò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́? +Gẹ́gẹ́ bí àṣà Paulu, ó wọ ibẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ. Fún ọ̀sẹ̀ mẹta ni ó fi ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́. +Nítorí ohun tí ò ń sọ ṣe àjèjì létí wa. A sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ rẹ̀.” +(Gbogbo àwọn ará Atẹni ní tiwọn, ati àwọn àlejò tí ó ń gbé ibẹ̀, kí wọn ṣá máa ròyìn nǹkan titun tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ̀lú ni iṣẹ́ tiwọn. Bí wọn bá ti gbọ́ èyí, ohun tí ó ń ṣe wọ́n tán.) +Paulu bá dìde dúró láàrin ìgbìmọ̀ tí ó wà ní Òkè Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Atẹni, ó hàn lọ́tùn-ún lósì sí ẹni tí ó bá wò ó pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ oriṣa ṣeré. +Bí mo ti ń lọ tí mò ń bọ̀ ni mò ń fojú wo àwọn ohun tí ẹ̀ ń sìn. Mo rí pẹpẹ ìrúbọ kan tí ẹ kọ àkọlé báyìí sí ara rẹ̀ pé: ‘Sí Ọlọrun tí ẹnìkan kò mọ̀.’ Ohun tí ẹ kò mọ̀ tí ẹ̀ ń sìn, òun ni mò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fun yín. +Ọlọrun tí ó dá ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, Oluwa ọ̀run ati ayé, kì í gbé ilé oriṣa àfọwọ́kọ́; +bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí kò ní, tí a óo sọ pé kí eniyan fún un, nítorí òun fúnra rẹ̀ ni ó ń fún gbogbo eniyan ní ẹ̀mí, èémí ati ohun gbogbo. +Òun ni ó dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti inú ẹnìkan ṣoṣo láti máa gbé gbogbo ilẹ̀ ayé. Kí ó tó dá wọn, ó ti ṣe ìpinnu tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí wọn yóo gbé ní ayé ati ààlà ibi tí wọn yóo máa gbé. +Ó dá wọn láti máa wá òun Ọlọrun, bí ó bá ṣeéṣe, kí wọ́n fọwọ́ kàn án, kí wọ́n rí i. Kò sì kúkú jìnnà sí ẹnìkan kan ninu wa. +Nítorí ẹnìkan sọ níbìkan pé:‘Ninu rẹ̀ ni à ń gbé,tí à ń rìn kiri,tí a wà láàyè.’Àwọn kan ninu àwọn akéwì yín pàápàá ti sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀; wọ́n ní,‘Ọmọ rẹ̀ ni a jẹ́.’ +Nígbà tí a jẹ́ ọmọ Ọlọrun, kò yẹ kí á rò pé Ọlọrun dàbí ère wúrà, tabi fadaka, tabi òkúta, ère tí oníṣẹ́ ọnà ṣe pẹlu ọgbọ́n ati èrò eniyan. +Ó ń ṣe àlàyé fún wọn, ó tún ń tọ́ka sí àkọsílẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ láti fihàn pé dandan ni kí Mesaya jìyà, kí ó jinde kúrò ninu òkú. Lẹ́yìn náà ó sọ fún wọn pé, Mesaya yìí náà ni Jesu tí òun ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wọn. +Ọlọrun ti fojú fo àkókò tí eniyan kò ní ìmọ̀ dá. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ó pàṣẹ fún gbogbo eniyan ní ibi gbogbo láti ronupiwada. +Nítorí ó ti yan ọjọ́ tí yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé nípa ọkunrin tí ó ti yàn. Ó fi òtítọ́ èyí han gbogbo eniyan nígbà tí ó jí ẹni náà dìde kúrò ninu òkú.” +Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé òkú jinde, àwọn kan ń ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn mìíràn ní, “A tún fẹ́ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí nígbà mìíràn.” +Paulu bá jáde kúrò láàrin wọn. +Àwọn kan ninu wọn bá fara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́. Ọ̀kan ninu wọn ni Dionisu, adájọ́ ní kóòtù Òkè Areopagu, ati obinrin kan tí ń jẹ́ Damarisi ati àwọn ẹlòmíràn pẹlu wọn. +Àwọn kan ninu wọn gbàgbọ́, wọ́n fara mọ́ Paulu ati Sila. Ọ̀pọ̀ ninu wọn jẹ́ Giriki, wọ́n ń sin Ọlọrun; pupọ ninu àwọn obinrin sì jẹ́ eniyan pataki-pataki. +Ṣugbọn ara ta àwọn Juu nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn eniyan pupọ gba ọ̀rọ̀ Paulu ati Sila. Wọ́n bá lọ mú ninu àwọn tí wọ́n ń fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀ kiri, àwọn jàgídíjàgan, wọ́n kó wọn jọ. Wọ́n bá dá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ninu ìlú. Wọ́n lọ ṣùrù bo ilé Jasoni, wọ́n ń wá Paulu ati Sila kí wọ́n lè fà wọ́n lọ siwaju àwọn ará ìlú. +Nígbà tí wọn kò rí wọn, wọ́n fa Jasoni ati díẹ̀ ninu àwọn onigbagbọ lọ siwaju àwọn aláṣẹ ìlú. Wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn tí wọn ń da gbogbo ayé rú nìyí; wọ́n ti dé ìhín náà. +Jasoni sì ti gbà wọ́n sílé. Gbogbo wọn ń ṣe ohun tí ó lòdì sí àṣẹ Kesari. Wọ́n ní: ọba mìíràn wà, ìyẹn ni Jesu!” +Ọkàn àwọn eniyan ati àwọn aláṣẹ ìlú dààmú nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí. +Wọ́n bá gba owó ìdúró lọ́wọ́ Jasoni ati àwọn yòókù, wọ́n bá dá wọn sílẹ̀. +Ìdàrúdàpọ̀ ní Tẹsalonika. +Lẹ́yìn èyí, Paulu kúrò ní Atẹni, ó lọ sí Kọrinti. +Nítorí n óo wà pẹlu rẹ. Kò sí ẹni tí yóo fọwọ́ kàn ọ́ láti ṣe ọ́ níbi. Nítorí mo ní eniyan pupọ ninu ìlú yìí.” +Paulu gbé ààrin wọn fún ọdún kan ati oṣù mẹfa, ó ń kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọrun. +Ṣugbọn nígbà tí Galio di gomina Akaya, àwọn Juu fi ohùn ṣọ̀kan láti dìde sí Paulu. Wọ́n bá mú un lọ sí kóòtù níwájú Galio. +Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń kọ́ àwọn eniyan láti sin Ọlọrun ní ọ̀nà tí ó lòdì sí òfin.” +Bí Paulu ti fẹ́ lanu láti fèsì, Galio sọ fún àwọn Juu pé, “Ẹ̀yin Juu, bí ó bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kan tabi ọ̀ràn burúkú kan ni ẹ mú wá, ǹ bá gbọ́ ohun tí ẹ ní sọ; +ṣugbọn tí ó bá jẹ́ àríyànjiyàn nípa àwọn ọ̀rọ̀ tabi orúkọ, tabi òfin yín, ẹ lọ rí sí i fúnra yín. N kò fẹ́ dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.” +Ni ó bá lé wọn kúrò ní kóòtù. +Ni gbogbo wọ́n bá mú Sositene, olórí ilé ìpàdé àwọn Juu, wọ́n ń lù ú níwájú kóòtù. Ṣugbọn Galio kò pé òun rí wọn. +Paulu tún dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i. Lẹ́yìn náà ó dágbére fún àwọn onigbagbọ, ó bá wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria; Pirisila ati Akuila bá a lọ. Paulu gé irun rẹ̀ ní ìlú Kẹnkiria nítorí pé ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan. +Nígbà tí wọ́n dé Efesu, Paulu fi Pirisila ati Akuila sílẹ̀, ó lọ sinu ilé ìpàdé àwọn Juu, ó lọ bá àwọn Juu sọ̀rọ̀. +Ó rí Juu kan níbẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akuila, ará Pọntu. Òun ati Pirisila iyawo rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Itali dé ni, nítorí ọba Kilaudiu pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Juu kúrò ní ìlú Romu. Paulu bá lọ sọ́dọ̀ wọn. +Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn fún àkókò díẹ̀ sí i, ṣugbọn kò gbà. +Bí ó ti fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó ní, “N óo tún pada wá sí ọ̀dọ̀ yín bí Ọlọrun bá fẹ́.” Ó bá kúrò ní Efesu. +Nígbà tí ó gúnlẹ̀ ní Kesaria, ó lọ kí ìjọ ní Jerusalẹmu. Lẹ́yìn náà ó lọ sí Antioku. +Ó dúró níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Ó bá tún kúrò, ó la agbègbè Galatia ati ti Firigia já, ó ń mú gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn le. +Ọkunrin Juu kan, ará Alẹkisandria, dé sí Efesu. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Apolo. Ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu rẹ̀, ó sì mọ Ìwé Mímọ́ pupọ. +A ti fi ọ̀nà Oluwa kọ́ ọ, a máa sọ̀rọ̀ pẹlu ìtara; a sì máa kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jesu ní àkọ́yé. Ṣugbọn ìrìbọmi tí Johanu ṣe nìkan ni ó mọ̀. +Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹlu ìgboyà ninu ilé ìpàdé àwọn Juu. Nígbà tí Pirisila ati Akuila gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un, wọ́n túbọ̀ fi ọ̀nà Ọlọrun yé e yékéyéké. +Nígbà tí ó fẹ́ kọjá lọ sí Akaya, àwọn onigbagbọ ní Efesu fún un ní ìwúrí, wọ́n kọ ìwé sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Akaya pé kí wọ́n gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀. Nígbà tí Apolo dé Akaya, ó wúlò lọpọlọpọ fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ níbẹ̀. +Bí ó bá bá àwọn Juu jiyàn níwájú gbogbo àwùjọ, a máa borí wọn, kedere ni ó ń fihàn láti inú Ìwé Mímọ́ pé Jesu ni Mesaya. +Nítorí pé iṣẹ́ kan náà ni wọ́n ń ṣe, Paulu lọ wọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó sì ń ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ ọnà awọ tí wọ́n fi ń ṣe àgọ́ ni wọ́n ń ṣe. +Ní gbogbo Ọjọ́ Ìsinmi, a máa bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀; ó fẹ́ yí àwọn Juu ati Giriki lọ́kàn pada. +Nígbà tí Sila ati Timoti dé láti Masedonia, Paulu wá fi gbogbo àkókò rẹ̀ sílẹ̀ fún iwaasu, ó ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu pé Jesu ni Mesaya. +Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan takò ó, tí wọn ń sọ ìsọkúsọ, ó gbọn ẹ̀wù rẹ̀ sí wọn lójú, ó ní, “Ẹ̀jẹ̀ yín wà lọ́rùn yín. Ọwọ́ tèmi mọ́. Láti ìgbà yìí lọ èmi yóo lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.” +Ni ó bá kúrò níbẹ̀, ó wọ ilé ẹnìkan tí ó ń jẹ́ Titiu Jusitu, ẹnìkan tí ń sin Ọlọrun. Ilé rẹ̀ fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹlu ilé ìpàdé àwọn Juu. +Kirisipu, ẹni tí ń darí ètò ilé ìpàdé àwọn Juu gba Oluwa gbọ́ pẹlu gbogbo ilé rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni pupọ ninu àwọn ará Kọrinti; nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa, wọ́n gbàgbọ́, wọ́n bá ṣe ìrìbọmi. +Ní alẹ́ ọjọ́ kan, Paulu rí ìran kan. Ninu ìran náà Oluwa sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, máa waasu, má dákẹ́. +Iṣẹ́ Paulu ní Kọrinti. +Nígbà tí Apolo wà ní Kọrinti, Paulu gba ọ̀nà ilẹ̀ la àwọn ìlú tí ó wà ní àríwá Antioku kọjá títí ó fi dé Efesu. Ó rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu mélòó kan níbẹ̀. +Báyìí ló ṣe fún ọdún meji, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo àwọn tí ń gbé Esia: ati Juu ati Giriki, ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa. +Ọlọrun fún Paulu lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu tóbẹ́ẹ̀ +tí àwọn eniyan fi ń mú ìdikù tabi aṣọ-iṣẹ́ tí ó ti kan ara Paulu, lọ fi lé àwọn aláìsàn lára, àìsàn wọn sì ń fi wọ́n sílẹ̀, ẹ̀mí burúkú sì ń jáde kúrò lára wọn. +Àwọn Juu kan tí wọ́n ti ń kiri láti ìlú dé ìlú, tí wọn ń lé ẹ̀mí burúkú jáde kúrò ninu àwọn eniyan, fẹ́ máa ṣe bíi Paulu nípa pípe orúkọ Oluwa Jesu lé àwọn tí ó ní ẹ̀mí burúkú lórí. Wọ́n á máa wí pé, “Mo pàṣẹ fun yín lórúkọ Jesu tí Paulu ń ròyìn nípa rẹ̀.” +Àwọn Juu meje kan tí wọn jẹ́ ọmọ Sikefa Olórí Alufaa wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀. +Ẹni tí ẹ̀mí burúkú wà ninu rẹ̀ bá bi wọ́n pé, “Mo mọ Jesu; mo sì mọ Paulu. Tiyín ti jẹ́?” +Ni ọkunrin tí ẹ̀mí burúkú wà ninu rẹ̀ bá fò mọ́ wọn; ó gbé ìjà ńlá kò wọ́n, ó sì ṣẹgun gbogbo wọn, ó ṣe wọ́n léṣe tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá jáde ninu ilé náà ní ìhòòhò, tàwọn ti ọgbẹ́ lára. +Gbogbo àwọn Juu ati àwọn Giriki tí ó ń gbé Efesu ni wọ́n gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ̀rù ba gbogbo wọn; wọ́n sì gbé orúkọ Jesu Oluwa ga. +Pupọ ninu àwọn onigbagbọ ni wọ́n jẹ́wọ́ ohun tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n tún tú àṣírí idán tí wọn ń pa. +Àwọn mélòó kan ninu àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kó ìwé idán wọn jọ, wọ́n bá dáná sun wọ́n lójú gbogbo eniyan. Nígbà tí wọ́n ṣírò iye owó àwọn ìwé ọ̀hún, wọ́n rí i pé ó tó ọ̀kẹ́ meji ààbọ̀ (50,000) owó fadaka. +Ó bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́ nígbà tí ẹ gba Jesu gbọ́?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o! A kò tilẹ̀ gbọ́ ọ rí pé nǹkankan wà tí ń jẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.” +Báyìí ni ọ̀rọ̀ Oluwa fi agbára hàn; ó ń tàn kálẹ̀, ó sì ń lágbára. +Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, Paulu pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti gba Masedonia lọ sí Akaya, kí ó wá ti ibẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu. Ó ní, “Nígbà tí mo bá dé ibẹ̀, ó yẹ kí n fojú ba Romu náà.” +Ó bá rán àwọn meji ninu àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, Timoti ati Erastu, lọ sí Masedonia ṣugbọn òun alára dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i ní Esia. +Ní àkókò náà, rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀, tí kì í ṣe kékeré, nípa ọ̀nà Oluwa. +Ọkunrin kan wà tí ń jẹ́ Demeteriu, alágbẹ̀dẹ fadaka. A máa fi fadaka ṣe ilé ìsìn ti oriṣa Atẹmisi; èyí a sì máa mú èrè pupọ wá fún àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ọnà yìí. +Demeteriu wá pe àpèjọ àwọn alágbẹ̀dẹ fadaka ati àwọn tí iṣẹ́ wọn fara jọra. Ó ní, “Ẹ̀yin eniyan wa, ẹ mọ̀ pé ninu iṣẹ́ yìí ni a ti ń rí èrè wa. +Ẹ wá rí i, ẹ tún ti gbọ́ pé kì í ṣe ní Efesu nìkan ni, ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé ní gbogbo Esia ni Paulu yìí ti ń yí ọ̀pọ̀ eniyan lọ́kàn pada. Ó ní àwọn ohun tí a fọwọ́ ṣe kì í ṣe oriṣa! +Ewu wà fún wa pé, iṣẹ́ wa yóo di ohun tí eniyan kò ní kà sí mọ́. Ṣugbọn èyí nìkan kọ́, ewu tí ó tún wà ni pé, ilé ìsìn oriṣa ńlá wa, Atẹmisi, yóo di ohun tí ẹnikẹ́ni kò ní ṣújá mọ́. Láìpẹ́ kò sí ẹni tí yóo gbà pé oriṣa wa tóbi mọ́, oriṣa tí gbogbo Esia ati gbogbo àgbáyé ń sìn!” +Nígbà tí wọ́n gbọ́, inú bí wọn pupọ. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń wí pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!” +Ni gbogbo ìlú bá dàrú. Wọ́n mú Gaiyu ati Arisitakọsi ará Masedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu ninu ìrìn àjò rẹ̀, gbogbo wọn bá rọ́ lọ sí ilé-ìṣeré. +Paulu tún bi wọ́n pé, “Ìrìbọmi ti ta ni ẹ ṣe?”Wọ́n ní, “Ìrìbọmi ti Johanu ni.” +Paulu fẹ́ wọ ibẹ̀ lọ bá àwọn èrò ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kò gbà fún un. +Àwọn ọ̀rẹ́ Paulu kan tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ní agbègbè Esia ranṣẹ lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó má yọjú sí ilé-ìṣeré nítorí gbogbo àwùjọ ti dàrú. +Bí àwọn kan ti ń kígbe bákan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń kígbe bá mìíràn. Ọpọlọpọ kò tilẹ̀ mọ ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi péjọ! +Àwọn mìíràn rò pé Alẹkisanderu ni ó dá gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, nítorí òun ni àwọn Juu tì siwaju. Alẹkisanderu fúnra rẹ̀ gbọ́wọ́ sókè, ó fẹ́ bá àwọn èrò sọ̀rọ̀. +Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Juu ni, wọ́n figbe ta, wọ́n ń pariwo fún ìwọ̀n wakati meji. Wọ́n ń kígbe pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!” +Akọ̀wé ìgbìmọ̀ ìlú ló mú kí wọ́n dákẹ́. Ó wá sọ pé, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni kò mọ̀ pé ìlú Efesu ni ó ń tọ́jú ilé ìsìn Atẹmisi oriṣa ńlá, ati òkúta rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run? +Kò sí ẹni tí ó lè wí pé kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kí ẹ fara balẹ̀ nígbà náà; kí a má fi ìwàǹwára ṣe ohunkohun. +Nítorí àwọn ọkunrin tí ẹ mú wá yìí, kò ja ilé oriṣa lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ ìsọkúsọ sí oriṣa wa. +Bí Demeteriu ati àwọn oníṣẹ́ ọnà tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnikẹ́ni, kóòtù wà; àwọn gomina sì ń bẹ. Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ pe ara wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀. +Bí ẹ bá tún ní ọ̀rọ̀ mìíràn tí ó jù yìí lọ, a óo máa yanjú rẹ̀ ní ìgbà tí a bá ń ṣe ìpàdé. +Paulu bá sọ pé, “Ìrìbọmi pé a ronupiwada ni Johanu ṣe. Ó ń sọ fún àwọn eniyan pé kí wọ́n gba ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́. Ẹni náà ni Jesu.” +Nítorí bí a ò bá ṣọ́ra, a óo dé ilé ẹjọ́ fún ìrúkèrúdò ọjọ́ òní, kò sì sí ohun tí a lè sọ pé ó fà á bí wọ́n bá bi wá.” +Lẹ́yìn tí ó ti sọ báyìí tán, ó tú àwọn eniyan náà ká. +Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbà fún Paulu, ó sì rì wọ́n bọmi lórúkọ Oluwa Jesu. +Nígbà tí Paulu gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé wọn, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. +Gbogbo àwọn ọkunrin náà tó mejila. +Paulu wọ inú ilé ìpàdé lọ. Fún oṣù mẹta ni ó fi ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìgboyà; ó ń fi ọ̀rọ̀ yé àwọn eniyan nípa ìjọba Ọlọrun, ó ń gbìyànjú láti yí wọn lọ́kàn pada. +Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan ṣe agídí, tí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ burúkú sí ọ̀nà Oluwa níwájú gbogbo àwùjọ, Paulu yẹra kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó kó àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ sí gbọ̀ngàn Tirani, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ níbẹ̀ lojoojumọ. +Paulu Dé Efesu. +Ní ọjọ́ Pẹntikọsti, gbogbo wọn wà pọ̀ ní ibìkan náà. +ilẹ̀ Firigia ati ilẹ̀ Pamfilia; ilẹ̀ Ijipti ati agbègbè Libia lẹ́bàá Kirene; àwọn àlejò láti ìlú Romu, +àwọn Juu ati àwọn aláwọ̀ṣe ẹ̀sìn Juu; àwọn ará Kirete ati àwọn ará Arabia, gbogbo wa ni a gbọ́ tí wọ́n ń sọ àwọn iṣẹ́ ńlá Ọlọrun ní oríṣìíríṣìí èdè wa.” +Ìdààmú bá gbogbo àwọn eniyan, ó pá wọn láyà. Wọ́n ń bi ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ èyí?” +Ṣugbọn àwọn mìíràn ń ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n ní, “Wọ́n ti mu ọtí yó ni!” +Peteru wá dìde dúró pẹlu àwọn aposteli mọkanla, ó sọ̀rọ̀ sókè, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin Juu, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ye yín, kí ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. +Àwọn yìí kò mutí yó bí ẹ ti rò, nítorí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni. +Ṣugbọn ohun tí Joẹli, wolii Ọlọrun ti sọ wá ṣẹ lónìí, tí ó wí pé, +‘Ọlọrun sọ pé, “Nígbà tí ó bá di àkókò ìkẹyìn,n óo tú Ẹ̀mí mi jáde sórí gbogbo eniyan.Àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin yóo sọ àsọtẹ́lẹ̀àwọn ọdọmọkunrin yín yóo rí ìran,àwọn àgbà yín yóo sì lá àlá. +Àní, ní àkókò náà, n óo tú Ẹ̀mí misórí àwọn ẹrukunrin miati sí orí àwọn ẹrubinrin mi,àwọn náà yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. +N óo fi ohun ìyanu hàn lókè ọ̀run,ati ohun abàmì lórí ilẹ̀ ayé;ẹ̀jẹ̀, ati iná, ìkùukùu ati èéfín. +Lójijì ìró kan dún láti ọ̀run, ó dàbí ìgbà tí afẹ́fẹ́ líle bá ń fẹ́, ó sì kún gbogbo inú ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó. +Oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá yóo di ẹ̀jẹ̀,kí ó tó di ọjọ́ ńlá tí ó lókìkí, ọjọ́ Oluwa. +Ní ọjọ́ náà gbogbo ẹni tí óbá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” ’ +“Ẹ̀yin ará, ọmọ Israẹli, ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Jesu ará Nasarẹti ni ẹni tí Ọlọrun ti fihàn fun yín pẹlu iṣẹ́ agbára, iṣẹ́ ìyanu, iṣẹ́ abàmì tí Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín. Ẹ̀yin fúnra yín sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. +Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun ati ètò tí Ọlọrun ti ṣe tẹ́lẹ̀, a fi í le yín lọ́wọ́, ẹ jẹ́ kí àwọn aláìbìkítà fún Òfin kàn án mọ́ agbelebu, ẹ sì pa á. +Ṣugbọn Ọlọrun tú ìdè ikú, ó jí i dìde ninu òkú! Kò jẹ́ kí ikú ní agbára lórí rẹ̀. +Nítorí Dafidi sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Mo rí Oluwa níwájú mi nígbà gbogbo,ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún minítorí náà ohunkohun kò lè dà mí láàmú. +Nítorí náà inú mi dùn, mo bú sẹ́rìn-ín.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan ẹlẹ́ran-ara ni mí,sibẹ n óo gbé ìgbé-ayé mi pẹlu ìrètí; +nítorí o kò ní fi ọkàn mi sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú;bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́. +O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí,O óo sì fi ayọ̀ kún ọkàn mi níwájú rẹ.’ +“Ẹ̀yin ará, mo sọ fun yín láìṣe àní-àní pé Dafidi baba-ńlá wa kú, a sì sin ín; ibojì rẹ̀ wà níhìn-ín títí di òní. +Wọ́n rí nǹkankan tí ó dàbí ahọ́n iná, tí ó pín ara rẹ̀, tí ó sì bà lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. +Ṣugbọn nítorí ó jẹ́ aríran, ó sì mọ̀ pé Ọlọrun ti búra fún òun pé ọ̀kan ninu ọmọ tí òun óo bí ni yóo jókòó lórí ìtẹ́ òun, +ó ti rí i tẹ́lẹ̀ pé Mesaya yóo jí dìde kúrò ninu òkú. Ìdí nìyí tí ó fi sọ pé,‘A kò fi í sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú;bẹ́ẹ̀ ni ẹran-ara rẹ̀ kò díbàjẹ́.’ +Jesu yìí ni Ọlọrun jí dìde. Gbogbo àwa yìí sì ni ẹlẹ́rìí. +Nisinsinyii tí a ti gbé e ka ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó wá tú u jáde. Ohun tí ẹ̀ ń rí, tí ẹ sì ń gbọ́ nìyí. +Nítorí Dafidi kò gòkè lọ sí ọ̀run. Ohun tí Dafidi sọ ni pé, ‘Oluwa wí fún oluwa mi pé:Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi +títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di tìmùtìmù ìtìsẹ̀ rẹ.’ +“Nítorí náà kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájú pé Jesu yìí tí ẹ̀yin kàn mọ́ agbelebu ni Ọlọrun ti fi ṣe Oluwa ati Mesaya!” +Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ọ̀rọ̀ náà gún wọn lọ́kàn. Wọ́n wá bi Peteru ati àwọn aposteli yòókù pé, “Ẹ̀yin ará, kí ni kí á wá ṣe?” +Peteru dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ronupiwada, kí á ṣe ìrìbọmi fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ní orúkọ Kristi. A óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín, ẹ óo wá gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. +Nítorí ẹ̀yin ni a ṣe ìlérí yìí fún, ati àwọn ọmọ yín ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn; a ṣe é fún gbogbo ẹni tí Oluwa Ọlọrun wa bá pè.” +Gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ oríṣìíríṣìí èdè mìíràn gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn láti máa sọ. +Ó tún bá wọn sọ̀rọ̀ pupọ, ó ń rọ̀ wọ́n gidigidi, pé, “Ẹ gba ara yín kúrò ninu ìyà tí ìran burúkú yìí yóo jẹ.” +A ṣe ìrìbọmi fún àwọn tí wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà. Ní ọjọ́ náà àwọn ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan ni a kà kún ọmọ ìjọ. +Wọ́n ń fi tọkàntọkàn kọ́ ẹ̀kọ́ tí àwọn aposteli ń kọ́ wọn; wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀, wọ́n jọ ń jẹun; wọ́n jọ ń gbadura. +Ẹ̀rù àwọn onigbagbọ wá ń ba gbogbo eniyan. Ọpọlọpọ ni iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì tí a ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe. +Gbogbo àwọn onigbagbọ wà ní ibìkan náà. Wọ́n jọ ní ohun gbogbo ní àpapọ̀. +Wọ́n ta gbogbo ohun tí wọ́n ní, wọ́n sì pín owó tí wọ́n rí láàrin ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti ṣe aláìní sí. +Wọ́n ń fi ọkàn kan lọ sí Tẹmpili lojoojumọ. Wọ́n jọ ń jẹun láti ilé dé ilé. Wọ́n jọ ń jẹun pẹlu ayọ̀ ati pẹlu ọkàn kan. +Wọ́n ń fi ìyìn fún Ọlọrun. Gbogbo àwọn eniyan ni ó fẹ́ràn wọn. Lojoojumọ ni àwọn tí wọ́n rí ìgbàlà ń dara pọ̀ mọ́ wọn. +Ní àkókò náà, àwọn Juu tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn ti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé wá, wọ́n wà ní Jerusalẹmu. +Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró yìí, àwọn eniyan rọ́ wá. Ẹnu yà wọ́n nítorí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọ́ tí wọn ń sọ èdè tirẹ̀. +Èyí dà wọ́n láàmú, ó sì yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ní, “Ṣebí ará Galili ni gbogbo àwọn tí ó ń sọ̀rọ̀ wọnyi? +Kí ló dé tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa fi gbọ́ tí wọn ń sọ èdè abínibí rẹ̀? +Ati ará Patia, ati ará Media ati ará Elamu; àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ Mesopotamia, ilẹ̀ Judia ati ilẹ̀ Kapadokia; ilẹ̀ Pọntu, ilẹ̀ Esia, +Bí Ẹ̀mí Mímọ́ Ti Ṣe Dé. +Nígbà tí rògbòdìyàn náà kásẹ̀, Paulu ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ó gbà wọ́n níyànjú, ó sì dágbére fún wọn, ó bá lọ sí Masedonia. +Paulu bá sọ̀kalẹ̀, ó gbá a mú, ó dùbúlẹ̀ lé e lórí. Ó ní, “Ẹ má dààmú, nítorí ẹ̀mí rẹ̀ ṣì wà ninu rẹ̀.” +Nígbà tí ó pada sókè, ó gé burẹdi, ó jẹun. Ó wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. Ó bá jáde lọ. +Wọ́n mú ọmọ náà lọ sílé láàyè. Èyí sì tù wọ́n ninu lọpọlọpọ. +A bọ́ siwaju, a wọkọ̀ ojú omi lọ sí Asọsi. Níbẹ̀ ni a lérò pé Paulu yóo ti wá bá wa tí òun náà yóo sì wọkọ̀. Òun ló ṣe ètò bẹ́ẹ̀ nítorí ó fẹ́ fẹsẹ̀ rìn dé ibẹ̀. +Nígbà tí ó bá wa ní Asọsi, ó wọnú ọkọ̀ wa, a bá lọ sí Mitilene. +Ní ọjọ́ keji a kúrò níbẹ̀, a dé òdìkejì erékùṣù Kiosi. Ní ọjọ́ kẹta a dé Samosi. Ní ọjọ́ kẹrin a dé Miletu. +Nítorí Paulu ti pinnu láti wọkọ̀ kọjá Efesu, kí ó má baà pẹ́ pupọ ní Esia, nítorí ó ń dàníyàn pé bí ó bá ṣeéṣe, òun fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Pẹntikọsti ní Jerusalẹmu. +Láti Miletu, Paulu ranṣẹ sí Efesu kí wọ́n lọ pe àwọn alàgbà ìjọ wá. +Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ bí mo ti lo gbogbo àkókò mi láàrin yín láti ìgbà tí mo ti kọ́kọ́ dé ilẹ̀ Esia. +Ẹ mọ̀ bí mo ti fi ìrẹ̀lẹ̀ ati omi ojú sin Oluwa ní ọ̀nà gbogbo ninu àwọn ìṣòro tí mo fara dà nítorí ọ̀tẹ̀ tí àwọn Juu dì sí mi. +Bí ó ti ń kọjá ní gbogbo agbègbè náà, bẹ́ẹ̀ ni ó ń gba àwọn eniyan níyànjú pẹlu ọ̀rọ̀ ìwúrí pupọ títí ó fi dé ilẹ̀ Giriki. +Ẹ mọ̀ pé n kò dánu dúró láti sọ ohunkohun fun yín tí yóo ṣe yín ní anfaani; mò ń kọ yín ní gbangba ati ninu ilé yín. +Mò ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu ati àwọn Giriki pé kí wọn yipada sí Ọlọrun, kí wọn ní igbagbọ ninu Oluwa Jesu. +Nisinsinyii, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti darí mi, mò ń lọ sí Jerusalẹmu láì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí mi níbẹ̀, +àfi pé láti ìlú dé ìlú ni Ẹ̀mí Mímọ́ ń fi àmì hàn mí pé ẹ̀wọ̀n ati ìyà ń dúró dè mí níbẹ̀. +Ṣugbọn n kò ka ẹ̀mí mi sí ohunkohun tí ó ní iye lórí fún ara mi. Ohun tí mò ń lépa ni láti parí iré ìje mi ati iṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Oluwa mi Jesu, èyí ni pé kí n tẹnu mọ́ ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. +“Wàyí ò, èmi gan-an mọ̀ pé gbogbo ẹ̀yin tí mo ti ń waasu ìjọba Ọlọrun láàrin yín kò tún ní fi ojú kàn mí mọ́. +Nítorí náà mo sọ fun yín lónìí yìí pé bí ẹnikẹ́ni bá ṣègbé ninu yín, ẹ̀bi mi kọ́. +Nítorí n kò dánu dúró láti sọ gbogbo ohun tí Ọlọrun fẹ́ fun yín. +Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀. +Mo mọ̀ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, àwọn ẹhànnà ìkookò yóo wọ ààrin yín; wọn kò sì ní dá agbo sí. +Ó ṣe oṣù mẹta níbẹ̀. Bí ó ti fẹ́ máa lọ sí Siria, ó rí i pé àwọn Juu ń dìtẹ̀ sí òun, ó bá gba Masedonia pada. +Mo mọ̀ pé láàrin yín àwọn ẹlòmíràn yóo dìde tí wọn yóo fi irọ́ yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn pada láti tẹ̀lé wọn. +Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra. Ẹ ranti pé fún ọdún mẹta, tọ̀sán-tòru ni n kò fi sinmi láti máa gba ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níyànjú pẹlu omi lójú. +“Nisinsinyii, mo fi yín lé Ọlọrun lọ́wọ́ ati ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó lè mu yín dàgbà, tí ó sì lè fun yín ní ogún pẹlu gbogbo àwọn tí a ti sọ di mímọ́. +N kò ṣe ojúkòkòrò owó tabi aṣọ tabi góòlù ẹnikẹ́ni. +Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé ọwọ́ ara mi yìí ni mo fi ṣiṣẹ́ tí mo fi ń gbọ́ bùkátà mi ati ti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi. +Mo ti fihàn yín pé bẹ́ẹ̀ ni a níláti ṣiṣẹ́ láti ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. Kí á máa ranti àwọn ọ̀rọ̀ Oluwa Jesu, nítorí òun fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Ayọ̀ pọ̀ ninu kí a máa fúnni ní nǹkan ju kí á máa gbà lọ.’ ” +Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kúnlẹ̀ pẹlu gbogbo wọn, ó sì gbadura. +Gbogbo wọn bá ń sunkún. Wọ́n ń dì mọ́ ọn, wọ́n ń fi ẹnu kò ó lẹ́nu. +Èyí tí ó dùn wọ́n jù ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ, pé wọn kò tún ní rí ojú òun mọ́. Wọ́n bá sìn ín lọ sí ìdíkọ̀. +Sopata ọmọ Pirusi ará Beria bá a lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni Arisitakọsi ati Sekundu; ará Tẹsalonika ni wọ́n. Gaiyu ará Dabe ati Timoti náà bá a lọ, ati Tukikọsi ati Tirofimọsi; àwọn jẹ́ ará Esia. +Àwọn tí a wí yìí ṣiwaju wa lọ, wọ́n lọ dúró dè wá ní Tiroasi. +Àwa náà wá wọkọ̀ ojú omi ní Filipi lẹ́yìn Àjọ̀dún Àìwúkàrà, a bá wọn ní Tiroasi lọ́jọ́ karun-un. Ọjọ́ meje ni a lò níbẹ̀. +Ní alẹ́ ọjọ́ Satide, a péjọ láti jẹun; Paulu wá ń bá àwọn onigbagbọ sọ̀rọ̀. Ó ti wà lọ́kàn rẹ̀ pé lọ́jọ́ keji ni òun óo tún gbéra. Nítorí náà ó sọ̀rọ̀ títí dòru. +Àtùpà pọ̀ ninu iyàrá òkè níbi tí a péjọ sí. +Ọdọmọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Yutiku jókòó lórí fèrèsé. Ó ti sùn lọ níbi tí Paulu gbé ń sọ̀rọ̀ lọ títí. Nígbà tí oorun wọ̀ ọ́ lára, ó ré bọ́ sílẹ̀ láti orí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kẹta. Nígbà tí wọn óo gbé e, ó ti kú. +Paulu lọ sí Masedonia ati Ilẹ̀ Giriki. +Nígbà tí a dágbére fún wọn tán, ọkọ̀ ṣí. A wá lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ keji a dé Rodọsi. Láti ibẹ̀ a lọ sí Patara. +A wà níbẹ̀ fún ọjọ́ pupọ. Nígbà tí à ń wí yìí ni Agabu aríran kan dé láti Judia. +Nígbà tí ó wá sọ́dọ̀ wa, ó mú ọ̀já ìgbànú Paulu, ó fi de ara rẹ̀ tọwọ́-tẹsẹ̀. Ó ní, “Ẹ gbọ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí: Báyìí ni àwọn Juu yóo di ọkunrin tí ó ni ọ̀já ìgbànú yìí ní Jerusalẹmu; wọn yóo sì fà á lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́.” +Nígbà tí a gbọ́ ohun tí Agabu wí, àwa ati àwọn tí ó ń gbé ibẹ̀ bẹ Paulu pé kí ó má lọ sí Jerusalẹmu. +Ṣugbọn Paulu dáhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ̀ ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi? Mo ti múra ẹ̀wọ̀n ati ikú pàápàá ní Jerusalẹmu nítorí orúkọ Oluwa Jesu.” +Nígbà tí a kò lè yí i lọ́kàn pada, a bá dákẹ́. A ní, “Ìfẹ́ Oluwa ni kí ó ṣẹ.” +Lẹ́yìn tí a gbé ọjọ́ bíi mélòó kan ni Kesaria, a palẹ̀ mọ́, a bá gbọ̀nà, ó di Jerusalẹmu. +Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Kesaria bá wa lọ. Wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ ẹni tí a óo dé sí ilé rẹ̀, Minasoni ará Kipru kan báyìí tí ó ti di onigbagbọ tipẹ́tipẹ́. +Nígbà tí a dé Jerusalẹmu, àwọn onigbagbọ gbà wá tayọ̀tayọ̀. +Ní ọjọ́ keji, Paulu bá lọ sọ́dọ̀ Jakọbu. Gbogbo àwọn àgbààgbà ni wọ́n pésẹ̀ sibẹ. +Nígbà tí Paulu kí wọn tán, ó ròyìn lẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ tí Ọlọrun lo òun láti ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. +A rí ọkọ̀ ojú omi kan níbẹ̀ tí ó fẹ́ sọdá lọ sí Fonike. Ni a bá wọ̀ ọ́, ọkọ̀ bá ṣí. +Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun. Àwọn náà wá sọ fún un pé, “Wò ó ná, arakunrin, ṣé o mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn Juu tí ó gba Jesu gbọ́, tí gbogbo wọn sì ní ìtara sí Òfin Mose. +Wọ́n ń sọ nípa rẹ pé ò ń kọ́ gbogbo àwọn Juu tí ń gbé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pé kí wọ́n yapa kúrò ninu ìlànà Mose. Wọ́n ní o sọ pé kí wọn má kọ ọmọ wọn nílà; àtipé kí wọn má tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn mọ́. +Èwo ni ṣíṣe? Ó dájú pé wọn á gbọ́ pé o ti dé. +Bí a bá ti wí fún ọ ni kí o ṣe. Àwọn ọkunrin mẹrin kan wà lọ́dọ̀ wa tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́. +Mú wọn, kí o lọ bá wọn wẹ ẹ̀jẹ́ náà kúrò. San gbogbo owó tí wọn óo bá ná ati tìrẹ náà. Kí wọn wá fá orí wọn. Èyí yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé kò sí òótọ́ ninu gbogbo nǹkan tí wọn ń sọ nípa rẹ. Wọn yóo mọ̀ pé Juu hánún-hánún ni ọ́ àtipé ò ń pa Òfin Mose mọ́. +Ní ti àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n gba Jesu gbọ́, a ti kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n yẹra fún oúnjẹ tí a ti fi rúbọ sí oriṣa, ati ẹ̀jẹ̀, ati ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí wọn sì ṣọ́ra fún àgbèrè.” +Ní ọjọ́ keji, Paulu mú àwọn ọkunrin náà, ó ṣe ètò láti wẹ ẹ̀jẹ́ wọn kúrò, ati tirẹ̀ pẹlu. Ó wọ Tẹmpili lọ láti lọ ṣe ìfilọ̀ ọjọ́ tí àkókò ìwẹ̀nùmọ́ wọn yóo parí, tí òun yóo mú ọrẹ ti ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn wá. +Nígbà tí ọjọ́ meje náà fẹ́rẹ̀ pé, àwọn Juu láti Esia rí Paulu ninu Tẹmpili. Wọ́n bá ké ìbòòsí láàrin gbogbo èrò, wọ́n sì dọwọ́ bo Paulu, +wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ gbani o! Ọkunrin tí ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo láti lòdì sí orílẹ̀-èdè wa ati Òfin Mose ati ilé yìí nìyí. Ó tún mú àwọn Giriki wọ inú Tẹmpili; ó wá sọ ibi mímọ́ yìí di àìmọ́.” +Wọ́n sọ báyìí nítorí pé wọ́n ti kọ́kọ́ rí Tirofimọsi ará Efesu pẹlu Paulu láàrin ìlú, wọ́n wá ṣebí Paulu mú un wọ inú Tẹmpili ni. +Nígbà tí à ń wo Kipru lókèèrè, a gba ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ibẹ̀ kọjá, a bá ń bá ọkọ̀ lọ sí ilẹ̀ Siria. A gúnlẹ̀ ní ìlú Tire, nítorí níbẹ̀ ni wọ́n fẹ́ já ẹrù ọkọ̀ sí. +Gbogbo ìlú bá dàrú. Àwọn eniyan ń rọ́ lọ sọ́dọ̀ Paulu. Wọ́n bá mú un, wọ́n wọ́ ọ jáde kúrò ninu Tẹmpili. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá ti gbogbo ìlẹ̀kùn. +Wọ́n fẹ́ pa á ni ìròyìn bá kan ọ̀gá àwọn ọmọ-ogun pé gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú. +Lójú kan náà ó bá mú àwọn ọmọ-ogun pẹlu àwọn balogun ọ̀rún tí ó wà lábẹ́ rẹ̀, ó sáré lọ bá wọn. Nígbà tí àwọn èrò rí ọ̀gágun ati àwọn ọmọ-ogun, wọ́n dáwọ́ dúró, wọn kò lu Paulu mọ́. +Ọ̀gágun bá súnmọ́ Paulu, ó mú un, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é. Ó wá wádìí ẹni tí ó jẹ́ ati ohun tí ó ṣe. +Àwọn kan ninu èrò ń sọ nǹkankan; àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn. Nígbà tí ọ̀gágun náà kò lè mọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà nítorí ariwo èrò, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun. +Nígbà tí wọ́n dé àtẹ̀gùn ilé, gbígbé ni àwọn ọmọ-ogun níláti gbé Paulu wọlé nítorí ojú àwọn èrò ti ranko. +Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan ni wọ́n ń tẹ̀lé wọn, tí wọn ń kígbe pé, “Ẹ pa á!” +Bí wọ́n ti fẹ́ mú Paulu wọ inú àgọ́ ọmọ-ogun, ó sọ fún ọ̀gágun pé, “Ṣé kò léèwọ̀ bí mo bá bá ọ sọ nǹkankan?”Ọ̀gágun wá bi í léèrè pé, “O gbọ́ èdè Giriki? +Ìyẹn ni pé kì í ṣe ìwọ ni ará Ijipti tí ó dá rúkèrúdò sílẹ̀ láìpẹ́ yìí, tí ó kó ẹgbaaji (4000) àwọn agúnbẹ lẹ́yìn lọ sí aṣálẹ̀?” +Paulu dáhùn ó ní, “Juu ni mí, ará Tasu ní ilẹ̀ Silisia. Ọmọ ìlú tí ó lókìkí ni mí. Gbà mí láàyè kí n bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀.” +A bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kan níbẹ̀, a bá dúró tì wọ́n níbẹ̀ fún ọjọ́ meje. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yìí sọ ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ fihàn wọ́n fún Paulu pé kí ó má lọ sí Jerusalẹmu. +Nígbà tí ó gbà fún un, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó gbọ́wọ́ sókè kí àwọn eniyan lè dákẹ́. Nígbà tí wọ́n dákẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ní èdè àwọn Heberu. +Nígbà tí ọjọ́ tí a óo gbé níbẹ̀ pé, a gbéra láti máa bá ìrìn àjò wa lọ. Gbogbo wọn ati àwọn iyawo wọn ati àwọn ọmọ wọn sìn wá dé ẹ̀yìn odi. A bá kúnlẹ̀ lórí iyanrìn ní èbúté, a gbadura. +Ni a bá dágbére fún ara wa, a wọ inú ọkọ̀, àwọn sì pada lọ sí ilé wọn. +Láti Tire, a bá ń bá ìrìn àjò wa lọ títí a fi dé Tolemaisi. Níbẹ̀ a lọ kí àwọn onigbagbọ, a sì dúró lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ kan. +Ní ọjọ́ keji, a gbéra, a lọ sí Kesaria. A wọ ilé Filipi, ajíyìnrere, ọ̀kan ninu àwọn meje tí àwọn ìjọ Jerusalẹmu yàn ní ijọ́sí. Lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a dé sí. +Ó ní ọmọbinrin mẹrin. Wundia ni wọ́n, wọn a sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. +Ìrìn Àjò Paulu sí Jerusalẹmu. +Ó ní “Ẹ̀yin ará mi ati ẹ̀yin baba wa, ẹ fetí sí ẹjọ́ tí mo ní í rò fun yín nisinsinyii.” +Mo bá bèèrè pé, ‘Kí ni kí n ṣe Oluwa?’ Oluwa bá dá mi lóhùn pé, ‘Dìde kí o máa lọ sí Damasku. Níbẹ̀ a óo sọ fún ọ gbogbo nǹkan tí a ti ṣètò fún ọ láti ṣe.’ +N kò lè ríran mọ́ nítorí ìmọ́lẹ̀ náà mọ́lẹ̀ pupọ. Àwọn ẹni tí ó wà pẹlu mi bá fà mí lọ́wọ́ lọ sí Damasku. +“Lẹ́yìn náà ni ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania dé. Ó jẹ́ olùfọkànsìn nípa ti Òfin Mose; gbogbo àwọn ẹni tí ń gbé Judia ni wọ́n sì jẹ́rìí rere nípa rẹ̀. +Ó dúró tì mí, ó ní, ‘Saulu arakunrin, lajú!’ Lẹsẹkẹsẹ ojú mi là, mo bá gbójú sókè wò ó. +Ó bá sọ fún mi pé, Ọlọrun àwọn baba wa ni ó yàn mí tẹ́lẹ̀ pé kí n mọ ìfẹ́ rẹ̀, kí n fojú rí iranṣẹ Olódodo rẹ̀, kí n sì gbọ́ ohùn òun pàápàá; +kí n lè ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ níwájú gbogbo eniyan nípa ohun tí mo rí, ati ohun tí mo gbọ́. +Ó wá bèèrè pé, kí ni mo tún ń fẹ́ nisinsinyii? Ó ní kí n dìde, kí n ṣe ìrìbọmi, kí n wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù, kí n pe orúkọ Oluwa. +“Nígbà tí mo ti pada sí Jerusalẹmu, bí mo ti ń gbadura ninu Tẹmpili, mo rí ìran kan. +Mo rí Oluwa tí ó ń sọ fún mi pé, ‘Jáde kúrò ní Jerusalẹmu kíákíá, nítorí wọn kò ní gba ẹ̀rí tí ò ń jẹ́ nípa mi.’ +Mo dáhùn, mo ní, ‘Oluwa, àwọn gan-an mọ̀ pé èmi ni mo máa ń sọ àwọn tí ó bá gbà ọ́ gbọ́ sẹ́wọ̀n, tí mo sì máa ń nà wọ́n káàkiri láti ilé ìpàdé kan dé ekeji. +Nígbà tí wọ́n gbọ́ tí ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, wọ́n pa lọ́lọ́. Paulu bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó ní, +Wọ́n mọ̀ pé nígbà tí wọ́n pa Stefanu, ẹlẹ́rìí rẹ, bí mo ti dúró nìyí, tí mò ń kan sáárá sí àwọn tí ó pa á tí mò ń ṣọ́ aṣọ wọn.’ +Ṣugbọn Oluwa sọ fún mi pé, ‘Bọ́ sọ́nà, nítorí n óo rán ọ lọ sí ọ̀nà jíjìn, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Juu.’ ” +Àwọn eniyan fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí gbolohun yìí fi jáde. Nígbà tí wọ́n gbọ́ gbolohun yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Ẹ pa irú ẹni bẹ́ẹ̀ rẹ́ kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láàyè!” +Wọ́n bá ń pariwo, wọ́n ń fi aṣọ wọn, wọ́n sì ń da ìyẹ̀pẹ̀ sókè. +Ni ọ̀gágun bá pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu wọ àgọ́ ọmọ-ogun lọ. Ó ní kí wọn nà án kí wọn fi wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, kí ó lè mọ ìdí tí àwọn eniyan ṣe ń pariwo lé e lórí bẹ́ẹ̀. +Bí wọ́n ti ń dè é mọ́lẹ̀ láti máa nà án, Paulu bi balogun ọ̀rún tí ó dúró pé, “Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti na ọmọ-ìbílẹ̀ Romu láì tíì dá a lẹ́jọ́?” +Nígbà tí balogun ọ̀rún gbọ́, ó lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, ó bi í pé, “Kí lẹ fẹ́ ṣe? Ọmọ ìbílẹ̀ Romu ni ọkunrin yìí o!” +Ní ọ̀gágun bá lọ bi Paulu, ó ní, “Wí kí n gbọ́, ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni ọ́?”Paulu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” +Ọ̀gágun náà bá dá a lóhùn pé, “Ọpọlọpọ owó ni mo ná kí n tó di ọmọ-ìbílẹ̀ Romu.”Ṣugbọn Paulu ní, “Ní tèmi o, wọ́n bí mi bẹ́ẹ̀ ni.” +Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ bá bìlà. Ẹ̀rù wá ba ọ̀gágun náà nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni Paulu, àtipé òun ti fi ẹ̀wọ̀n dè é. +“Juu ni mí, Tasu ní ilẹ̀ Silisia la gbé bí mi. Ní ìlú yìí ni a gbé tọ́ mi dàgbà. Ilé-ìwé Gamalieli ni mo lọ, ó sì kọ́ mi dáradára nípa Òfin ìbílẹ̀ wa. Mo ní ìtara fún Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti ní lónìí. +Lọ́jọ́ keji, ọ̀gágun náà tú Paulu sílẹ̀. Ó fẹ́ mọ òtítọ́ ẹ̀sùn tí àwọn Juu mú wá nípa rẹ̀. Ó bá pàṣẹ pé kí àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ. Ó bá mú Paulu lọ siwaju wọn. +Mo ṣe inúnibíni sí ọ̀nà ẹ̀sìn yìí. Gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé Jesu ni mò ń lé kiri: ẹni tí mo bá sì bá ninu wọn pípa ni. Èmi a mú wọn, èmi a dè wọ́n, wọn a sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, atọkunrin atobinrin wọn. +Olórí Alufaa pàápàá lè jẹ́rìí mi, ati gbogbo àwọn àgbààgbà. Ọwọ́ wọn ni mo ti gba ìwé lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin wa ní Damasku. Mo lọ sibẹ láti de àwọn ẹlẹ́sìn yìí kí n sì mú wọn wá sí Jerusalẹmu láti jẹ wọ́n níyà. +“Bí mo ti ń lọ, tí mo súnmọ́ Damasku, lójijì, ní ọ̀sán gangan, ìmọ́lẹ̀ ńlá kan láti ọ̀run tàn yí mi ká. +Mo bá ṣubú lulẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó ń sọ fún mi pé, ‘Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’ +Mo wá dáhùn, mo ní, ‘Ta ni ọ́, Oluwa?’ Ó bá sọ fún mi pé, ‘Èmi ni Jesu ará Nasarẹti, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.’ +Àwọn tí wọ́n wà pẹlu mi rí ìmọ́lẹ̀ náà, ṣugbọn wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀. +Paulu Sọ Bí Ó Ṣe Di Onigbagbọ. +Paulu kọjú sí àwọn ìgbìmọ̀, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ní gbogbo ìgbé-ayé mi, ọkàn mí mọ́ níwájú Ọlọrun títí di òní.” +Nígbà tí àríyànjiyàn náà pọ̀ pupọ, ẹ̀rù ba ọ̀gágun pé kí wọn má baà fa Paulu ya. Ó bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ogun kí wọn wá fi agbára mú Paulu kúrò láàrin wọn, kí wọn mú un wọnú àgọ́ àwọn ọmọ-ogun lọ. +Ní òru ọjọ́ keji, Oluwa dúró lẹ́bàá Paulu, ó ní, “Ṣe ọkàn rẹ gírí. Gẹ́gẹ́ bí o ti jẹ́rìí iṣẹ́ mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni o níláti jẹ́rìí nípa mi ní Romu náà.” +Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Juu péjọ pọ̀ láti dìtẹ̀ sí Paulu. Wọ́n búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu. +Àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ yìí ju bí ogoji lọ. +Wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà, wọ́n ní, “A ti jẹ́jẹ̀ẹ́, a sì ti búra pé a kò ní fẹnu kan nǹkankan títí a óo fi pa Paulu. +A fẹ́ kí ẹ̀yin ati gbogbo wa ranṣẹ sí ọ̀gá àwọn ọmọ-ogun pé kí ó fi Paulu ranṣẹ sí yín nítorí ẹ fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fínnífínní. Ní tiwa, a óo ti múra sílẹ̀ láti pa á kí ó tó dé ọ̀dọ̀ yín.” +Ṣugbọn ọmọ arabinrin Paulu kan gbọ́ nípa ète yìí. Ó bá lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun, ó lọ ròyìn fún Paulu. +Paulu wá pe ọ̀kan ninu àwọn balogun ọ̀rún, ó ní, “Mú ọdọmọkunrin yìí lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, nítorí ó ní ọ̀rọ̀ kan láti sọ fún un.” +Balogun ọ̀rún náà bá mú un lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun. Ó ní, “Ẹlẹ́wọ̀n t�� ń jẹ́ Paulu ni ó pè mí, tí ó ní kí n mú ọdọmọkunrin yìí wá sọ́dọ̀ yín nítorí ó ní ọ̀rọ̀ kan láti sọ fun yín.” +Ọ̀gágun náà bá fà á lọ́wọ́, ó mú un lọ sí kọ̀rọ̀. Ó wá bi í pé, “Kí ni o ní sọ fún mi?” +Bí ó ti sọ báyìí, bẹ́ẹ̀ ni Anania Olórí Alufaa sọ fún àwọn tí ó dúró ti Paulu pé kí wọ́n gbá a lẹ́nu. +Ọdọmọkunrin náà wá dáhùn pé, “Àwọn Juu ti fohùn ṣọ̀kan láti bẹ̀ yín pé kí ẹ mú Paulu wá siwaju ìgbìmọ̀ lọ́la kí àwọn le wádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní fínnífínní. +Ẹ má gbà fún wọn. Nítorí àwọn kan ninu wọn yóo dènà dè é, wọ́n ju ogoji lọ. Wọ́n ti búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu. Bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ti múra tán. Ohun tí wọn ń retí ni kí ẹ ṣe ìlérí pé ẹ óo fi Paulu ranṣẹ sí ìgbìmọ̀.” +Ọ̀gágun bá ní kí ọdọmọkunrin náà máa lọ. Ó kìlọ̀ fún un pé kí ó má sọ fún ẹnikẹ́ni pé ó ti fi ọ̀rọ̀ yìí tó òun létí. +Ọ̀gágun náà bá pe meji ninu àwọn balogun ọ̀rún tí ó wà lábẹ́ rẹ̀, ó ní, “Ẹ lọ mú igba ọmọ-ogun ati aadọrin ẹlẹ́ṣin ati igba ọmọ-ogun tí ó ní ọ̀kọ̀. Ẹ óo lọ sí Kesaria. Kí ẹ múra láti lọ ní agogo mẹsan-an alẹ́. +Ẹ tọ́jú àwọn ẹṣin tí Paulu yóo gùn, kí ẹ sìn ín dé ọ̀dọ̀ Fẹliksi gomina ní alaafia.” +Ó wá kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́. Ìwé náà lọ báyìí: +“Gomina ọlọ́lá jùlọ, Fẹliksi, èmi Kilaudiu Lisia ki yín. +Àwọn Juu mú ọkunrin yìí, wọ́n fẹ́ pa á. Mo gbà á lọ́wọ́ wọn pẹlu àwọn ọmọ-ogun mi nítorí mo gbọ́ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni. +Mo fẹ́ mọ ìdí tí wọ́n ṣe fi ẹ̀sùn kàn án. Mo bá mú un lọ sí iwájú ìgbìmọ̀ wọn. +Mo rí i pé ẹ̀sùn tí wọ́n ní jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ òfin wọn; kò ṣe ohunkohun tí a lè fi sọ pé kí á pa á tabi kí á jù ú sí ẹ̀wọ̀n. +Paulu wá sọ fún un pé, “Ọlọrun yóo lù ọ́. Ìwọ ògiri tí wọ́n kùn lẹ́fun lásán yìí! O jókòó sibẹ, ò ń dá mi lẹ́jọ́ lórí Òfin, sibẹ o pa Òfin tì, o ní kí wọ́n lù mí.” +Nígbà tí ìròyìn kàn mí pé àwọn kan láàrin àwọn Juu ti dìtẹ̀ sí ọkunrin yìí, mo bá fi í ranṣẹ si yín. Mo ti sọ fún àwọn tí ó fi ẹ̀sùn kàn án pé kí wọ́n wá sọ ohun tí wọ́n ní sí i níwájú yín.” +Àwọn ọmọ-ogun ṣe bí a ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n mú Paulu lóru lọ sí ìlú Antipatiri. +Ní ọjọ́ keji wọ́n fi Paulu sílẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣin, wọ́n pada sí àgọ́ wọn. +Àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣin bá a lọ sí Kesaria. Wọ́n fún gomina ní ìwé, wọ́n sì fa Paulu lé e lọ́wọ́. +Gomina ka ìwé náà. Ó wá wádìí pé apá ibo ni Paulu ti wá. Wọ́n sọ fún un pé ní agbègbè Silisia ni. +Ó bá sọ fún un pé, “N óo gbọ́ ẹjọ́ rẹ nígbà tí àwọn tí ó fi ẹjọ́ rẹ sùn náà bá dé.” Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n máa ṣọ́ Paulu ní ààfin Hẹrọdu. +Àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ bá ní, “Olórí Alufaa Ọlọrun ni ò ń bú bẹ́ẹ̀?” +Paulu dáhùn pé, “Ará, n kò mọ̀ pé Olórí Alufaa ni. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ burúkú sí aláṣẹ àwọn eniyan rẹ.’ ” +Nígbà tí Paulu mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sadusi ni apá kan ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ìgbìmọ̀, àtipé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Farisi ni àwọn mìíràn, ó kígbe pé, “Ẹ̀yin ará, Farisi ni mí. Farisi ni àwọn òbí mi. Nítorí ìrètí wa pé àwọn òkú yóo jí dìde ni wọ́n ṣe mú mi wá dáhùn ẹjọ́.” +Nígbà tí ó sọ báyìí, ìyapa bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn Farisi ati àwọn Sadusi, ìgbìmọ̀ bá pín sí meji. +Nítorí àwọn Sadusi sọ pé kò sí ajinde, bẹ́ẹ̀ ni kò sí angẹli tabi àwọn ẹ̀mí; ṣugbọn àwọn Farisi gbà pé mẹtẹẹta wà. +Ni ariwo ńlá bá bẹ́ sílẹ̀. Àwọn amòfin kan ninu àwọn Farisi dìde, wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé, “Àwa kò rí nǹkan burúkú tí ọkunrin yìí ṣe. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀mí ni ó sọ̀rọ̀ fún un ńkọ́? Tabi angẹli?” +Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Paulu. +Lẹ́yìn ọjọ́ marun-un, Anania olórí Alufaa dé pẹlu àwọn àgbààgbà ati agbẹjọ́rò kan tí ń jẹ́ Tatulu. Wọ́n ro ẹjọ́ Paulu fún gomina. +Gomina wá mi orí sí Paulu. Paulu wá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tirẹ̀. Ó ní:“Ó dùn mọ́ mi pé níwájú yín ni n óo ti sọ ti ẹnu mi. Nítorí mo mọ̀ pé ẹ ti ń ṣe onídàájọ́ ní orílẹ̀-èdè wa yìí fún ọpọlọpọ ọdún. +Kò ju ọjọ́ mejila lọ nisinsinyii tí mo lọ ṣọdún ní Jerusalẹmu. Ẹ lè wádìí èyí. +Ẹnìkan kò rí mi kí n máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn ninu Tẹmpili. Bẹ́è�� ni ẹnìkan kò rí mi pé mo kó àwọn eniyan jọ láti dá rúkèrúdò sílẹ̀, ìbáà ṣe ninu ilé ìpàdé ni tabi níbikíbi láàrin ìlú. +Wọn kò lè rí ohunkohun wí tí ẹ lè rí dìmú ninu ẹjọ́ tí wọn wá ń rò mọ́ mi lẹ́sẹ̀ nisinsinyii. +Ṣugbọn mo jẹ́wọ́ ohun kan fun yín: lóòótọ́ ni mò ń sin Ọlọrun àwọn baba wa ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀. Mo gba gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé Òfin ati ninu ìwé àwọn wolii. +Mo sì ń wojú Ọlọrun nítorí pé mo ní ìrètí kan náà tí àwọn ará ibí yìí pàápàá tí wọn ń rojọ́ mi ní, pé gbogbo òkú ni yóo jinde, ati ẹni rere ati ẹni burúkú. +Ìdí nìyí tí mo fi ń sa ipá mi kí ọkàn mi lè jẹ́ mi lẹ́rìí pé inú mi mọ́ sí Ọlọrun ati eniyan nígbà gbogbo. +“Ó ti tó ọdún mélòó kan tí mo ti dé Jerusalẹmu gbẹ̀yìn. Ìtọrẹ àánú ni mo mú wá fún àwọn orílẹ̀-èdè mi, kí n sì rúbọ. +Níbi tí mo gbé ń ṣe èyí, wọ́n rí mi ninu Tẹmpili. Mo ti wẹ ara mi mọ́ nígbà náà. N kò kó èrò lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni n kò fa ìjàngbọ̀n. +Ṣugbọn àwọn Juu kan láti Esia wà níbẹ̀. Àwọn ni ó yẹ kí wọ́n wá siwaju yín bí wọn bá ní ẹ̀sùn kan sí mi. +Nígbà tí wọ́n pe Paulu, Tatulu bẹ̀rẹ̀ sí rojọ́. Ó ní:“Fẹliksi ọlọ́lá jùlọ, à ń jọlá alaafia tí ẹ mú wá lọpọlọpọ, a sì ń gbádùn oríṣìíríṣìí àtúnṣe tí ẹ̀ ń ṣe lọ́tùn-ún lósì fún àwọn ọmọ ilẹ̀ wa. +Tabi, kí àwọn tí wọ́n wà níhìn-ín fúnra wọn sọ nǹkan burúkú kan tí wọ́n rí pé mo ṣe nígbà tí mo wà níwájú ìgbìmọ̀. +Àfi gbolohun kan tí mo sọ nígbà tí mo dúró láàrin wọn, pé, ‘Ìdí tí a fi mú mi wá fún ìdájọ́ níwájú yín lónìí ni pé mo ní igbagbọ pé àwọn òkú yóo jinde.’ ” +Fẹliksi bá sún ọjọ́ ìdájọ́ siwaju. Ó mọ ohun tí ọ̀nà igbagbọ jẹ́ dáradára. Ó ní, “Nígbà tí ọ̀gágun Lisia bá dé, n óo sọ bí ọ̀rọ̀ yín ti rí lójú mi.” +Ó bá pàṣẹ fún balogun ọ̀rún pé kí ó máa ṣọ́ Paulu. Ó ní kí ó máa há a mọ́lé, ṣugbọn kí ó ní òmìnira díẹ̀, kí ó má sì dí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀. +Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí Fẹliksi ti dé pẹlu Durusila iyawo rẹ̀ tí ó jẹ́ Juu, ó ranṣẹ sí Paulu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu lẹ́nu rẹ̀. +Nígbà tí Paulu bẹ̀rẹ̀ sí sọ tirẹ̀ nípa ìwà rere, ìkóra-ẹni-níjàánu, ati ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Fẹliksi. Ó bá sọ fún Paulu pé, “Ó tó gẹ́ẹ́ lónìí. Máa lọ. Nígbà tí mo bá ráyè n óo tún ranṣẹ pè ọ́.” +Sibẹ ó ń retí pé Paulu yóo fún òun ní owó. Nítorí náà, a máa ranṣẹ pè é lemọ́lemọ́ láti bá a sọ̀rọ̀. +Lẹ́yìn ọdún meji Pọkiu Fẹstu gba ipò Fẹliksi. Nítorí Fẹliksi ń wá ojurere àwọn Juu, ó fi Paulu sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. +Ọjọ́ iwájú ni ẹ̀ ń rò tí ẹ fi ń ṣe èyí nígbà gbogbo. A dúpẹ́ pupọ lọ́wọ́ yín. +N kò fẹ́ gbà yín ní àkókò títí, mo bẹ̀ yín kí ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gbọ́ ohun tí a níláti sọ ní ṣókí. +Onijamba eniyan ni ọkunrin yìí; rúkèrúdò ni ó ń dá sílẹ̀ láàrin àwọn Juu ní gbogbo àgbáyé. Ọ̀gá ni ninu ẹgbẹ́ àwọn Nasarene. +A ká a mọ́ ibi tí ó ti fẹ́ mú ohun ẹ̀gbin wọ inú Tẹmpili, a bá mú un. [A fẹ́ jẹ ẹ́ níyà gẹ́gẹ́ bí òfin wa. +Ṣugbọn ọ̀gágun Lisia wá fi ipá gbà á kúrò lọ́wọ́ wa, ni ó bá mú un lọ. +Òun ni ó pàṣẹ pé kí àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án wá siwaju yín.] Bí ẹ bá wádìí lẹ́nu òun fúnrarẹ̀, ẹ óo rí i pé òtítọ́ ni gbogbo ẹjọ́ rẹ̀ tí a fi sùn yín.” +Àwọn Juu náà gbè é lẹ́sẹ̀; wọ́n ní bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó sọ rí. +Ẹ̀sùn Tí Wọ́n fi Kan Paulu. +Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta tí Fẹstu dé sí agbègbè ibi iṣẹ́ rẹ̀, ó lọ sí Jerusalẹmu láti Kesaria. +Paulu dáhùn ó ní, “Níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ ọba Kesari ni mo gbé dúró, níbẹ̀ ni a níláti dá ẹjọ́ mi. N kò ṣẹ àwọn Juu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti mọ̀ dájúdájú. +Bí mo bá rú òfin, tabi bí mo bá ṣe ohun tí ó yẹ kí á dá mi lẹ́bi ikú, n kò bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ má pa mí. Ṣugbọn bí kò bá sí ohun kan tí a lè rí dìmú ninu ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí, ẹnikẹ́ni kò lè fi mí wá ojurere wọn. Ẹ gbé ẹjọ́ mi lọ siwaju Kesari ọba.” +Fẹstu forí-korí pẹlu àwọn olùbádámọ̀ràn rẹ̀, ó wá dáhùn pé, “O ti gbé ẹjọ́ rẹ lọ siwaju ọba Kesari; nítorí náà o gbọdọ̀ lọ sọ́dọ̀ ọba Kesari.” +Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Agiripa ọba ati Berenike wá kí Fẹstu ní Kesaria. +Wọ́n pẹ́ díẹ̀ níbẹ̀. Fẹstu wá fi ọ̀rọ̀ Paulu siwaju ọba. Ó ní, “��kunrin kan wà níhìn-ín tí Fẹliksi fi sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. +Nígbà tí mo lọ sí Jerusalẹmu, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà àwọn Juu rojọ́ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ mí pé kí n dá a lẹ́bi. +Mo dá wọn lóhùn pé kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti fa ẹnikẹ́ni lé àwọn olùfisùn rẹ̀ lọ́wọ́ láì fún un ní anfaani láti fojúkojú pẹlu wọn, kí ó sì sọ ti ẹnu rẹ̀ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. +Nígbà tí wọ́n bá mi wá síhìn-ín, n kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀. Ní ọjọ́ keji mo jókòó ní kóòtù, mo pàṣẹ kí wọ́n mú ọkunrin náà wá. +Nígbà tí àwọn tí ó fi ẹ̀sùn kàn án dìde láti sọ̀rọ̀, wọn kò mẹ́nuba irú àwọn ọ̀ràn tí mo rò pé wọn yóo sọ. +Àríyànjiyàn nípa ẹ̀sìn oriṣa wọn, ati nípa ẹnìkan tí ń jẹ́ Jesu ni ohun tí wọn ń jà sí. Jesu yìí ti kú, ṣugbọn Paulu ní ó wà láàyè. +Àwọn olórí alufaa ati àwọn aṣiwaju àwọn Juu bá gbé ọ̀rọ̀ Paulu siwaju rẹ̀. Wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé +Ọ̀rọ̀ náà rú mi lójú; mo bá bi ọkunrin náà bí ó bá fẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, kí á ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ náà níbẹ̀. +Ṣugbọn Paulu ní kí á fi òun sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí Kesari yóo fi lè gbọ́ ẹjọ́ òun. Mo bá pàṣẹ kí wọ́n fi í sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí tí n óo fi lè fi ranṣẹ sí Kesari.” +Agiripa bá wí fún Fẹstu pé, “Èmi fúnra mi fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọkunrin náà.”Fẹstu dáhùn ó ní, “Ẹ óo gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ lọ́la.” +Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, Agiripa ati Berenike bá dé pẹlu ayẹyẹ. Wọ́n wọ gbọ̀ngàn ní ààfin pẹlu àwọn ọ̀gágun ati àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn ní ìlú. Fẹstu bá pàṣẹ kí wọ́n mú Paulu wá. +Fẹstu wá sọ pé, “Agiripa aláyélúwà ati gbogbo ẹ̀yin eniyan tí ẹ bá wa péjọ níbí. Ọkunrin tí ẹ̀ ń wò yìí ni gbogbo àwọn Juu ní Jerusalẹmu ati níbí ń yan eniyan wá rí mi nípa rẹ̀, tí wọn ń kígbe pé kò yẹ kí ó tún wà láàyè mọ́. +Ní tèmi n kò rí ohun kan tí ó ṣe tí ó fi jẹ̀bi ikú. Ṣugbọn nígbà tí òun fúnrarẹ̀ ní kí á gbé ẹjọ́ òun lọ sí ọ̀dọ̀ Kesari, mo pinnu láti fi í ranṣẹ. +Ṣugbọn n kò ní ohun kan pàtó láti kọ sí oluwa mi nípa rẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi mú un wá siwaju yín, pàápàá siwaju Agiripa aláyélúwà, kí n lè rí ohun tí n óo kọ nípa rẹ̀ lẹ́yìn tí a bá ti yẹ ọ̀rọ̀ náà wò. +Mo rò pé kò bójú mu kí á fi ẹlẹ́wọ̀n ranṣẹ láìsọ ẹ̀sùn tí a fi kàn án.” +kí ó ṣe oore kan fún wọn, kí ó fi Paulu ranṣẹ sí Jerusalẹmu. Èrò wọn ni láti dènà dè é, kí wọ́n baà lè pa á. +Ṣugbọn Fẹstu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọmọ-ogun ń ṣọ́ Paulu ní Kesaria; èmi náà kò sì ní pẹ́ pada sibẹ. +Ẹ jẹ́ kí àwọn aṣiwaju yín bá mi kálọ kí wọ́n wá sọ bí wọ́n bá ní ẹ̀sùn kan sí i.” +Kò lò ju bí ọjọ́ mẹjọ tabi mẹ́wàá lọ pẹlu wọn, ni ó bá pada lọ sí Kesaria. Ní ọjọ́ keji ó jókòó ninu kóòtù, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu wá. +Nígbà tí Paulu dé, àwọn Juu tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu tò yí i ká, wọ́n ń ro ẹjọ́ ńláńlá mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ lọ́tùn-ún lósì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ninu gbogbo ẹjọ́ tí wọ́n rò. +Nígbà tí Paulu bẹ̀rẹ̀ sí sọ ti ẹnu rẹ̀, ó ní, “N kò ṣe ohunkohun tí ó lòdì sí òfin àwọn Juu tabi sí Tẹmpili; n kò sì ṣẹ Kesari.” +Nítorí pé Fẹstu ń wá ojurere àwọn Juu, ó bi Paulu pé, “Ṣé o óo kálọ sí Jerusalẹmu, kí n dá ẹjọ́ yìí níbẹ̀?” +Paulu Gbé Ẹjọ́ Rẹ̀ Lọ siwaju Ọba Kesari. +Agiripa wá yíjú sí Paulu, ó ní, “Ọ̀rọ̀ kàn ọ́. Sọ tìrẹ.” Paulu bá nawọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ro ẹjọ́ tirẹ̀. Ó ní: +Mo ṣe díẹ̀ ní Jerusalẹmu. Pupọ ninu àwọn onigbagbọ ni mo tì mọ́lé, lẹ́yìn tí mo ti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí alufaa. Wọn á máa pa wọ́n báyìí, èmi náà á sì ní bẹ́ẹ̀ gan-an ló yẹ wọ́n. +Mò ń lọ láti ilé ìpàdé kan dé ekeji, mo sì ń jẹ wọ́n níyà, bóyá wọn a jẹ́ fẹnu wọn gbẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀tanú náà pọ̀ sí wọn tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi lé wọn dé ìlú òkèèrè pàápàá. +“Irú eré báyìí ni mò ń sá tí mò fi ń lọ sí Damasku ní ọjọ́ kan, pẹlu ìwé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa. +Kabiyesi, bí mo ti ń lọ lọ́nà lọ́sàn-án gangan, mo rí ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run tí ó mọ́lẹ̀ ju ti oòrùn lọ, tí ó tàn yí èmi ati àwọn tí ń bá mi lọ ká. +Bí gbogbo wa ti ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn kan tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu. Ó ní, ‘Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi? O óo fara pa bí o b�� ta igi ẹlẹ́gùn-ún nípàá.’ +Mo wá bèèrè pé, ‘Ìwọ ta ni, Oluwa?’ Oluwa bá dáhùn ó ní, ‘Èmi ni Jesu tí ò ń ṣe inúnibíni sí. +Dìde nàró. Ohun tí mo fi farahàn ọ́ nìyí: mo ti yàn ọ́ láti jẹ́ iranṣẹ mi, kí o lè jẹ́rìí ohun tí o rí, ati ohun tí n óo fihàn ọ́. +N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli ati àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí n óo rán ọ sí. +Kí á lè là wọ́n lójú, kí á sì lè yí wọn pada láti inú òkùnkùn sinu ìmọ́lẹ̀, kí á lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àṣẹ Satani, kí á sì fi wọ́n lé ọwọ́ Ọlọrun; kí wọ́n lè ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígbà mí gbọ́; kí wọ́n sì lè ní ogún pẹlu àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.’ +“Nítorí náà, Agiripa Ọba Aláyélúwà, n kò ṣe àìgbọràn sí ìran tí ó ti ọ̀run wá. +“Agiripa Ọba Aláyélúwà, mo ka ara mi sí olóríire pé níwájú yín ni n óo ti dáhùn sí gbogbo ẹjọ́ tí àwọn Juu pè mí lónìí, +Ṣugbọn mo kọ́kọ́ waasu fún àwọn tó wà ní Damasku, lẹ́yìn náà mo waasu fún àwọn tó wà ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo ilẹ̀ Judia, ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu. Mò ń kéde pé kí wọ́n ronupiwada, kí wọ́n yipada sí Ọlọrun, kí wọn máa ṣe ohun tí ó yẹ ẹni tí ó ti ronupiwada. +Ìdí nìyí tí àwọn Juu fi mú mi ninu Tẹmpili, tí wọn ń fẹ́ pa mí. +Ṣugbọn Ọlọrun ràn mí lọ́wọ́. Títí di ọjọ́ òní mo ti dúró láti jẹ́rìí fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki. N kò sọ ohunkohun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn wolii ati Mose sọ pé yóo ṣẹlẹ̀. +Èyí ni pé Mesaya níláti jìyà; àtipé òun ni yóo kọ́ jí dìde kúrò ninu òkú tí yóo sì kéde iṣẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu.” +Bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀ báyìí, Fẹstu ké mọ́ ọn pé, “Paulu, orí rẹ dàrú! Ìwé àmọ̀jù ti dà ọ́ lórí rú.” +Paulu dáhùn ó ní, “Fẹstu ọlọ́lá, orí mi kò dàrú. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ gan-an ni mò ń sọ. +Gbogbo nǹkan wọnyi yé Kabiyesi, nítorí náà ni mo ṣe ń sọ ọ́ láìfòyà. Ó dá mi lójú pé kò sí ohun tí ó pamọ́ fún un ninu gbogbo ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí kì í ṣe ní kọ̀rọ̀ ni nǹkan wọnyi ti ṣẹlẹ̀. +Agiripa Ọba Aláyélúwà, ṣé ẹ gba àwọn wolii gbọ́? Mo mọ̀ pé ẹ gbà wọ́n gbọ́.” +Agiripa bá bi Paulu pé, “Kíákíá báyìí ni o rò pé o lè sọ mí di Kristẹni?” +Paulu dáhùn, ó ní, “Ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ Ọlọrun ni pé, ó pẹ́ ni, ó yá ni, kí ẹ rí bí mo ti rí lónìí, láìṣe ti ẹ̀wọ̀n yìí. Kì í ṣe ẹ̀yin nìkan, ṣugbọn gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí.” +pàápàá nítorí ẹ mọ gbogbo àṣà àwọn Juu dáradára, ẹ sì mọ àríyànjiyàn tí ó wà láàrin wọn. Nítorí náà mo bẹ̀ yín kí ẹ fi sùúrù gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. +Agiripa bá dìde pẹlu gomina ati Berenike ati gbogbo àwọn tí ó jókòó pẹlu wọn. +Wọ́n bọ́ sápá kan, wọ́n ń sọ fún wọn pé, “Ọkunrin yìí kò ṣe ohunkohun tí ó fi jẹ̀bi ikú tabi ẹ̀wọ̀n.” +Agiripa wá sọ fún Fẹstu pé, “À bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀ bí kò bá jẹ́ pé ó ti ní kí á gbé ẹjọ́ òun lọ siwaju Kesari.” +“Gbogbo àwọn Juu ni wọ́n mọ̀ bí mo ti lo ìgbésí ayé mi láti ìbẹ̀rẹ̀ ní ìgbà èwe mi nígbà tí mò ń gbé Jerusalẹmu láàrin àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wa. +Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti mọ̀ mí. Bí wọn bá fẹ́, wọ́n lè jẹ́rìí sí i pé ọ̀nà àwọn Farisi ni mo tẹ̀lé ninu ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wa, ọ̀nà yìí ló sì le jù. +Wàyí ò! Ohun tí ó mú mi dúró nílé ẹjọ́ nisinsinyii ni pé mo ní ìrètí pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa yóo ṣẹ. +Ìrètí yìí ni àwọn ẹ̀yà mejila tí ó wà ní orílẹ̀-èdè wa ní, tí wọ́n ṣe ń fi ìtara sin Ọlọrun tọ̀sán-tòru. Nítorí ohun tí à ń retí yìí ni àwọn Juu fi ń rojọ́ mi, Kabiyesi! +Kí ló ṣe wá di ohun tí ẹnikẹ́ni ninu yín kò lè gbàgbọ́ pé Ọlọrun a máa jí òkú dìde?” +“Nígbà kan rí èmi náà rò pé ó jẹ mí lógún láti tako orúkọ Jesu ará Nasarẹti. Kí ni n ò ṣe tán? +Paulu Sọ Ti Ẹnu Rẹ̀ níwájú Agiripa. +Nígbà tí wọ́n pinnu láti fi wá ranṣẹ sí Itali, wọ́n fi Paulu ati àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn lé balogun ọ̀rún kan tí ó ń jẹ́ Juliọsi lọ́wọ́, ó jẹ́ ọ̀gágun ti ẹgbẹ́ kan tí wọn ń pè ní Ọmọ-ogun Augustu. +ó ní, “Ẹ̀yin ará, mo wòye pé ewu wà ninu ìrìn àjò yìí. Ọpọlọpọ nǹkan ni yóo ṣòfò: ẹrù inú ọkọ̀, ati ọkọ̀ fúnrarẹ̀. Ewu wà fún gbogbo àwa tí a wà ninu ọkọ̀ pàápàá.” +Ṣugbọn ọ̀rọ̀ atukọ̀ ati ẹni tó ni ọkọ̀ wọ ọ̀gágun létí ju ohun tí Paulu sọ lọ. +Ibi tí wọ́n wà kì í ṣe ibi tí ó dára láti gbé ní ìgbà òtútù. Nítorí náà pupọ ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ rò pé kí àwọn kúrò níbẹ̀, bóyá wọn yóo lè dé Fonike níbi tí wọn yóo lè dúró ní ìgbà òtútù. Èbúté kan ní Kirete ni Fonike; ó kọjú sí ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn gúsù ati ìwọ̀ oòrùn àríwá Kirete. +Nígbà tí afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ jẹ́jẹ́ láti apá gúsù, wọ́n rò pé ó ti bọ́ sí i fún wọn láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe. Wọ́n bá ṣíkọ̀, wọ́n ń pẹ́ ẹ̀bá Kirete lọ. +Kò pẹ́ pupọ ni afẹ́fẹ́ líle kan láti erékùṣù náà bá bì lu ọkọ̀. Wọ́n ń pe afẹ́fẹ́ náà ní èyí tí ó wá láti àríwá ìlà oòrùn. +Afẹ́fẹ́ líle yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí taari ọkọ̀. Nítorí pé kò sí ọ̀nà láti fi yí ọkọ̀, kí ó kọjú sí atẹ́gùn yìí, a fi í sílẹ̀ kí afẹ́fẹ́ máa gbé e lọ. +A sinmi díẹ̀ nígbà tí a gba gúsù erékùṣù kékeré kan tí ó ń jẹ́ Kauda kọjá. Níbẹ̀, a fi tipátipá so ọkọ̀ kékeré tí ó wà lára ọkọ̀ ńlá wa, kí ó má baà fọ́. +Wọ́n bá fà á sinu ọkọ̀ ńlá, wọ́n wá fi okùn so ó mọ́ ara ọkọ̀ ńlá. Ẹ̀rù ń bà wọ́n kí wọn má forí ọkọ̀ sọ ilẹ̀ iyanrìn ní Sitisi, wọ́n bá ta aṣọ-ọkọ̀, kí atẹ́gùn lè máa gbé ọkọ̀ náà lọ. +Ní ọjọ́ keji, nígbà tí ìjì túbọ̀ le pupọ, a bá da ẹrù inú ọkọ̀ sinu òkun. +Ní ọjọ́ kẹta, ọwọ́ ara wọn ni wọ́n fi da àwọn ohun èèlò inú ọkọ̀ náà sinu òkun. +A bá wọ ọkọ̀ ojú omi kan tí ó ń ti Adiramitu bọ̀ tí ó fẹ́ lọ sí ibi mélòó kan ní Esia. Ọkọ̀ bá ṣí; Arisitakọsi ará Tẹsalonika, ní ilẹ̀ Masedonia, ń bá wa lọ. +Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni oòrùn kò ràn tí ìràwọ̀ kò sì yọ. Ìjì ńlá ń jà. A bá sọ ìrètí nù pé a tún lè là mọ́. +Lẹ́yìn tí wọ́n ti wà fún ọpọlọpọ ọjọ́, láì jẹun, Paulu dìde dúró láàrin wọn, ó ní, “Ẹ̀yin eniyan, ẹ̀ bá ti gbọ́ tèmi kí ẹ má ṣíkọ̀ ní Kirete. Irú ewu ati òfò yìí ìbá tí sí. +Ṣugbọn bí ó ti rí yìí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ ṣara gírí. Ẹ̀mí ẹnikẹ́ni ninu yín kò ní ṣòfò; ọkọ̀ nìkan ni yóo ṣòfò. +Nítorí ní alẹ́ àná, angẹli Ọlọrun mi, tí mò ń sìn dúró tì mí, ó ní, +‘Má bẹ̀rù, Paulu. Dandan ni kí o dé iwájú Kesari. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé Ọlọrun ti fi ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹni tí ó wọkọ̀ pẹlu rẹ jíǹkí rẹ.’ +Nítorí náà ẹ̀yin eniyan, ẹ ṣara gírí, nítorí mo gba Ọlọrun gbọ́ pé bí ó ti sọ fún mi ni yóo rí. +Ṣugbọn ọkọ̀ wa yóo fàyà sọlẹ̀ ní erékùṣù kan.” +Nígbà tí ó di alẹ́ kẹrinla tí afẹ́fẹ́ ti ń ti ọkọ̀ wa kiri ninu òkun Adiria, àwọn atukọ̀ fura ní òru pé a kò jìnnà sí ilẹ̀. +Wọ́n sọ ìwọ̀n sinu òkun, wọ́n rí i pé ó jìn tó ogoji mita. Nígbà tí a sún díẹ̀, wọ́n tún sọ ìwọ̀n sinu òkun, wọ́n rí i pé ó jìn tó ọgbọ̀n mita. +Wọ́n wá ń bẹ̀rù pé kí ọkọ̀ má forí sọ òkúta. Wọ́n bá ju irin ìdákọ̀ró mẹrin sinu omi ní ẹ̀yìn ọkọ̀; wọ́n bá ń gbadura pé kí ilẹ̀ tètè mọ́. +Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Sidoni. Juliọsi ṣe dáradára sí Paulu. Ó jẹ́ kí ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí wọ́n fún un ní àwọn nǹkan tí ó nílò. +Àwọn atukọ̀ ń wá bí wọn yóo ti ṣe sálọ kúrò ninu ọkọ̀. Wọ́n bá sọ ọkọ̀ kékeré sórí òkun bí ẹni pé wọ́n fẹ́ sọ ìdákọ̀ró tí ó wà níwájú ọkọ̀ sinu òkun. +Paulu wá sọ fún balogun ọ̀rún ati àwọn ọmọ-ogun náà pé, “Bí àwọn ará ibí yìí kò bá dúró ninu ọkọ̀, kò sí bí ẹ ti ṣe lè là.” +Àwọn ọmọ-ogun bá gé okùn tí wọ́n fi so ọkọ̀ kékeré náà, wọ́n jẹ́ kí ìgbì gbé e lọ. +Nígbà tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́, Paulu gbà wọ́n níyànjú pé kí gbogbo wọn jẹun. Ó ní, “Ó di ọjọ́ mẹrinla lónìí, tí ọkàn yín kò tíì balẹ̀ tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀; tí ẹ kò jẹ ohunkohun. +Nítorí náà, mo bẹ̀ yín, ẹ jẹun; èyí ṣe pataki bí ẹ ò bá fẹ́ kú. Irun orí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ ní ṣòfò.” +Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, òun náà mú burẹdi, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun níwájú gbogbo wọn, ó bù ú, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́. +Ni gbogbo wọn bá ṣara gírí, àwọn náà bá jẹun. +Gbogbo àwa tí a wà ninu ọkọ̀ náà jẹ́ igba ó lé mẹrindinlọgọrin (276). +Nígbà tí wọ́n jẹun yó tán, wọ́n da ọkà tí ó kù sinu òkun láti mú kí ọkọ̀ lè fúyẹ́ sí i. +Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n rí èbúté ṣugbọn wọn kò mọ ibẹ̀. Wọ́n wá ṣe akiyesi ibìkan tí òkun ti wọ ààrin ilẹ̀ tí ó ní iyanrìn. Wọ́n rò pé bóyá àwọn lè tukọ̀ dé èbúté ibẹ̀. +Láti ibẹ̀, a ṣíkọ̀, nítorí pé afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wa, a gba apá Kipru níbi tí afẹ́fẹ́ kò ti fẹ́ pupọ. +Wọ́n bá já àwọn ìdákọ̀ró, wọ́n jẹ́ kí wọ́n rì sinu omi. Ní àkókò yìí kan náà, wọ́n tú okùn lára àwọn ajẹ̀ tí wọ́n fi ń tukọ̀. Wọ́n wá ta aṣọ-ọkọ̀ tí ó wà lókè patapata níwájú ọkọ̀. Atẹ́gùn wá ń fẹ́ ọkọ̀ lọ sí èbúté. +Ṣugbọn ọkọ̀ rọ́lu ilẹ̀ níbi tí òkun kò jìn, ni ó bá dúró gbọnin. Iwájú ọkọ̀ wọ inú iyanrìn, kò ṣe é yí. Ẹ̀yìn ọkọ̀ kò kanlẹ̀, ìgbì wá bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ọ bí ó ti ń bì lù ú. +Àwọn ọmọ-ogun wá ń gbèrò pé kí àwọn pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n, kí wọn má baà lúwẹ̀ẹ́ sálọ. +Ṣugbọn balogun ọ̀rún kò jẹ́ kí àwọn ọmọ-ogun ṣe ìfẹ́ inú wọn, nítorí pé ó fẹ́ mú Paulu gúnlẹ̀ ní alaafia. Ó pàṣẹ pé kí àwọn tí ó bá lè lúwẹ̀ẹ́ kọ́kọ́ bọ́ sómi, kí wọ́n lúwẹ̀ẹ́ lọ sí èbúté. +Kí àwọn yòókù wá tẹ̀lé wọn, kí wọ́n dì mọ́ pákó tabi kí wọ́n dì mọ́ ara ọkọ̀ tí ó ti fọ́. Báyìí ni gbogbo wa ṣe gúnlẹ̀ ní alaafia. +A la agbami lọ sí apá èbúté Silisia ati Pamfilia títí a fi dé ìlú Mira ní ilẹ̀ Lisia. +Níbẹ̀ ni balogun ọ̀rún tí ó ń mú wa lọ ti rí ọkọ̀ Alẹkisandria kan tí ó ń lọ sí Itali. Ni a bá wọ̀ ọ́. +Fún ọpọlọpọ ọjọ́, ọkọ̀ kò lè yára rìn. Tipátipá ni a fi dé Kinidusi. Afẹ́fẹ́ ṣe ọwọ́ òdì sí wa. Ni a bá gba ẹ̀gbẹ́ Kirete níbi tí afẹ́fẹ́ kò ti fẹ́ pupọ. A kọjá ibi tí ilẹ̀ gbọọrọ ti wọ ààrin òkun tí wọn ń pè ní Salimone. +Tipátipá ni a fi ń lọ lẹ́bàá èbúté títí a fi dé ibìkan tí wọn ń pè ní Èbúté-rere tí kò jìnnà sí ìlú Lasia. +A pẹ́ níbẹ̀. Ewu ni bí a bá fẹ́ máa bá ìrìn àjò wa lọ nítorí ọjọ́ ààwẹ̀ ti kọjá. Paulu bá gbà wọ́n níyànjú; +Paulu Wọkọ̀ Lọ sí Romu. +Nígbà tí a ti gúnlẹ̀ ní alaafia tán ni a tó mọ̀ pé Mẹlita ni wọ́n ń pe erékùṣù náà. +Wọ́n yẹ́ wa sí pupọ. Nígbà tí a óo sì fi ṣíkọ̀, wọ́n fún wa ní àwọn nǹkan tí a lè nílò lọ́nà. +Lẹ́yìn oṣù mẹta tí a ti wà níbẹ̀, a wọ ọkọ̀ ojú omi Alẹkisandria kan tí ó ti dúró ní erékùṣù yìí fún ìgbà òtútù. Ó ní ère ìbejì níwájú rẹ̀. +Nígbà tí a dé Sirakusi, a dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. +Láti ibẹ̀ a ṣíkọ̀, a dé Regiumu. Ní ọjọ́ keji, afẹ́fẹ́ kan láti gúsù fẹ́ wá, ni a bá tún ṣíkọ̀. Ní ọjọ́ kẹta a dé Puteoli. +A rí àwọn onigbagbọ níbẹ̀. Wọ́n rọ̀ wá kí á dúró lọ́dọ̀ wọn, a bá ṣe ọ̀sẹ̀ kan níbẹ̀. Báyìí ni a ṣe dé Romu. +Àwọn onigbagbọ ibẹ̀ ti gbọ́ ìròyìn wa. Wọ́n bá wá pàdé wa lọ́nà, wọ́n dé Ọjà Apiusi ati Ilé-èrò Mẹta. Nígbà tí Paulu rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, èyí sì dá a lọ́kàn le. +Nígbà tí a wọ Romu, wọ́n gba Paulu láàyè láti wá ilé gbé pẹlu ọmọ-ogun kan tí wọ́n fi ṣọ́ ọ. +Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta Paulu pe àwọn aṣiwaju àwọn Juu jọ. Nígbà tí ẹsẹ̀ wọn pé, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin alàgbà, n kò ṣe ohunkohun tí ó lòdì sí àwọn eniyan wa tabi sí àṣà àwọn baba ńlá wa tí wọ́n fi fi mí lé àwọn ará Romu lọ́wọ́ tí wọ́n sì fi mí sinu ẹ̀wọ̀n láti Jerusalẹmu. +Nígbà tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu mi, wọ́n fẹ́ dá mi sílẹ̀ nítorí wọn kò rí ohunkohun tí mo ṣe tí wọ́n fi lè dá mi lẹ́bi ikú. +Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu kò gbà pé kí wọ́n dá mi sílẹ̀, kò sí ohun tí mo tún lè ṣe jù pé kí n gbé ẹjọ́ mi wá siwaju Kesari lọ. Kì í ṣe pé mo ní ẹjọ́ kankan láti bá orílẹ̀-èdè wa rò. +Àwọn ará ibẹ̀ ṣe ìtọ́jú wa lọpọlọpọ. Wọ́n fi ọ̀yàyà gba gbogbo wa. Wọ́n dáná fún wa nítorí pé òjò ti bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀, òtútù sì mú. +Ìdí nìyí tí mo fi ranṣẹ pè yín láti ri yín kí n sì ba yín sọ̀rọ̀; nítorí ohun tí Israẹli ń retí ni wọ́n ṣe fi ẹ̀wọ̀n so mí báyìí.” +Wọ́n dá a lóhùn pé, “A kò rí ìwé gbà nípa rẹ láti Judia; bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni ninu àwọn ará wa kò débí láti ròyìn rẹ tabi láti sọ̀rọ̀ rẹ ní ibi. +A rò pé ó dára kí á gbọ́ ohun tí o ní lọ́kàn, nítorí pé ó ti dé etígbọ̀ọ́ wa pé níbi gbogbo ni àwọn eniyan lòdì sí ẹgbẹ́ tí ó yàtọ̀ yìí.” +Wọ́n bá dá ọjọ́ tí wọn yóo wá fún un. Nígbà tí ọjọ́ pé, pupọ ninu wọn wá kí i. Ó bá dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀, ó ń fi tẹ̀dùntẹ̀dùn ṣe àlàyé ìjọba Ọlọrun fún wọn, ó sì ń fi ẹ̀rí tí ó wà ninu ìwé Òfin Mose ati ìwé wolii nípa Jesu hàn wọ́n láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. +Àwọn mìíràn gba ohun tí ó sọ gbọ́, ṣugbọn àwọn mìíràn kò gbàgbọ́. +Nígbà tí ohùn wọn kò dọ́gba láàrin ara wọn, wọ́n bá ń túká lọ. Paulu wá tún sọ gbolohun kan, ó ní, “Òtítọ́ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sọ láti ẹnu wolii Aisaya sí àwọn baba-ńlá yín. +Ó ní,‘Lọ sọ fún àwọn eniyan yìí pé:Ẹ óo fetí yín gbọ́, ṣugbọn kò ní ye yín;Ẹ óo wò ó títí, ṣugbọn ẹ kò ní mọ̀ ọ́n. +Nítorí ọkàn àwọn eniyan yìí kò ṣí; wọ́n ti di alágbọ̀ọ́ya,wọ́n ti dijú.Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀,wọn ìbá fi ojú wọn ríran,wọn ìbá fetí gbọ́ràn,òye ìbá yé wọn,wọn ìbá yipada;èmi ìbá sì wò wọ́n sàn.’ +“Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé a ti rán iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọrun yìí sí àwọn tí kì í ṣe Juu. Àwọn ní tiwọn yóo gbọ́.” +Nígbà tí Paulu ti sọ báyìí tán, àwọn Juu túká, wọ́n ń bá ara wọn jiyàn kíkankíkan. +Nígbà tí Paulu di ìdì igi kan, tí ó dà á sinu iná, bẹ́ẹ̀ ni paramọ́lẹ̀ kan yọ nígbà tí iná rà á, ló bá so mọ́ Paulu lọ́wọ́. +Fún ọdún meji gbáko ni Paulu fi gbé ninu ilé tí ó gbà fúnra rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ń gba gbogbo àwọn tí ó ń wá rí i. +Ó ń waasu ìjọba Ọlọrun. Ó ń kọ́ àwọn eniyan nípa Oluwa Jesu Kristi láì bẹ̀rù ohunkohun. Ẹnikẹ́ni kò sì dí i lọ́wọ́. +Nígbà tí àwọn ará Mẹlita rí ejò náà tí ó ń ṣe dìrọ̀dìrọ̀ ní ọwọ́ Paulu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkunrin yìí. Ó yọ ninu ewu òkun, ṣugbọn Ọlọrun ẹ̀san kò gbà pé kí ó yè.” +Paulu kàn gbọn ejò náà sinu iná ni, ohun burúkú kan kò sì ṣẹlẹ̀ sí i. +Àwọn eniyan ń retí pé ọwọ́ rẹ̀ yóo wú, tabi pé lójijì yóo ṣubú lulẹ̀, yóo sì kú. Nígbà tí wọ́n retí títí, tí wọn kò rí i kí nǹkankan ṣe é, wọ́n yí èrò wọn pada, wọ́n ní, “Irúnmọlẹ̀ ni!” +Ilẹ̀ tí ó wá yí wọn ká jẹ́ ti Pubiliusi, baálẹ̀ erékùṣù náà. Ó gbà wá sílé fún ọjọ́ mẹta, ó sì ṣe wá lálejò. +Ní àkókò yìí baba Pubiliusi ń ṣàìsàn: ibà ń ṣe é, ó sì ń ya ìgbẹ́-ọ̀rìn. Paulu bá wọ iyàrá tọ̀ ọ́ lọ. Lẹ́yìn tí ó gbadura, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì wò ó sàn. +Nígbà tí èyí ṣẹlẹ̀, àwọn yòókù tí ó ń ṣàìsàn ní erékùṣù náà bá ń wá sọ́dọ̀ Paulu, ó sì ń wò wọ́n sàn. +Ohun tí Paulu Ṣe ní Erékùṣù Mẹlita. +Ní agogo mẹta ọ̀sán, Peteru ati Johanu gòkè lọ sí Tẹmpili ní àkókò adura. +Wọ́n ṣe akiyesi pé ẹni tí ó ti máa ń jókòó ṣagbe lẹ́nu Ọ̀nà Dáradára Tẹmpili ni. Ẹnu yà wọ́n, wọ́n ta gìrì sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkunrin náà. +Bí ọkunrin náà ti rọ̀ mọ́ Peteru ati Johanu, gbogbo àwọn eniyan sáré pẹlu ìyanu lọ sọ́dọ̀ wọn ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí à ń pè ní ti Solomoni. +Nígbà tí Peteru rí wọn, ó bi àwọn eniyan pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, kí ló dé tí èyí fi yà yín lẹ́nu? Kí ló dé tí ẹ fi tẹjú mọ́ wa bí ẹni pé nípa agbára wa tabi nítorí pé a jẹ́ olùfọkànsìn ni a fi mú kí ọkunrin yìí rìn? +Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu, Ọlọrun àwọn baba wa ni ó dá Ọmọ rẹ̀, Jesu lọ́lá. Jesu yìí ni ẹ fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, òun ni ẹ sẹ́ níwájú Pilatu nígbà tí ó fi dá a sílẹ̀. +Ẹ sẹ́ ẹni Ọlọrun ati olódodo, ẹ wá bèèrè pé kí wọ́n dá apànìyàn sílẹ̀ fun yín; +ẹ pa orísun ìyè. Òun yìí ni Ọlọrun jí dìde kúrò ninu òkú. Àwa gan-an ni ẹlẹ́rìí pé bẹ́ẹ̀ ló rí. +Orúkọ Jesu ati igbagbọ ninu orúkọ yìí ni ó mú ọkunrin tí ẹ rí yìí lára dá. Ẹ ṣá mọ̀ ọ́n. Igbagbọ ninu rẹ̀ ni ó fún ọkunrin yìí ní ìlera patapata, gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti rí i fúnra yín. +“Ṣugbọn nisinsinyii, ará, mo mọ̀ pé ẹ kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjòyè yín náà kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é. +Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe mú ohun tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wolii rẹ̀ ṣẹ, pé Mesaya òun níláti jìyà. +Nítorí náà, ẹ ronupiwada, kí ẹ yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun bí ẹ bá fẹ́ kí á pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́. +Ọkunrin kan wà tí wọn máa ń gbé wá sibẹ, tí ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá. Lojoojumọ, wọn á máa gbé e wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili tí à ń pè ní “Ẹnu Ọ̀nà Dáradára,” kí ó lè máa ṣagbe lọ́dọ̀ àwọn tí ń wọ inú Tẹmpili lọ. +Nígbà náà, àkókò ìtura láti ọ̀dọ̀ Oluwa, yóo dé ba yín; Oluwa yóo wá rán Mesaya tí ó ti yàn tẹ́lẹ̀ si yín, èyí nnì ni Jesu, +ẹni tí ó níláti wà ní ọ̀run títí di àkókò tí ohun gbogbo yóo fi di titun, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ láti ìgbà àtijọ́, láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́, àwọn eniyan ọ̀tọ̀. +Mose ṣá ti sọ pé, ‘Oluwa Ọlọrun yín yóo gbé wolii kan bí èmi dìde láàrin àwọn arakunrin yín. Òun ni kí ẹ gbọ́ràn sí lẹ́nu ninu ohun gbogbo tí ó bá sọ fun yín. +Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbọ́ràn sí wolii náà lẹ́nu, píparun ni a óo pa á run patapata láàrin àwọn eniyan Ọlọrun.’ +Gbogbo àwọn wolii, láti ìgbà Samuẹli ati àwọn tí ó dé lẹ́yìn rẹ̀, fi ohùn ṣọ̀kan sí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ń sọ nípa àkókò yìí. +Ẹ̀yin gan-an ni ọmọ àwọn wolii; nítorí tiyín ni Ọlọrun ṣe bá àwọn baba yín dá majẹmu, nígbà tí ó sọ fún Abrahamu pé, ‘Nípa ọmọ rẹ ni n óo ṣe bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’ +Nígbà tí Ọlọrun gbé Ọmọ rẹ̀ dìde, ẹ̀yin ni ó kọ́kọ́ rán an sí, kí ó lè bukun yín láti mú kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀.” +Nígbà tí ó rí Peteru ati Johanu tí wọ́n fẹ́ wọ inú Tẹmpili, ó ní kí wọ́n ta òun lọ́rẹ. +Peteru ati Johanu tẹjú mọ́ ọn, Peteru ní, “Wò wá!” +Ọkunrin náà bá ń wò wọ́n, ó ń retí pé wọn yóo fún òun ní nǹkan. +Peteru bá sọ fún un pé, “N kò ní fadaka tabi wúrà, ṣugbọn n óo fún ọ ní ohun tí mo ní. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasarẹti, máa rìn.” +Ó bá fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó gbé e dìde. Lẹsẹkẹsẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ọrùn-ẹsẹ̀ rẹ̀ bá mókun. +Ó bá fò sókè, ó dúró, ó sì ń rìn. Ó bá tẹ̀lé wọn wọ inú Tẹmpili; ó ń rìn, ó ń fò sókè, ó sì ń yin Ọlọrun. +Gbogbo àwọn eniyan rí i tí ó ń rìn, tí ó ń yin Ọlọrun. +A Wo Arọ Kan Sàn Lẹ́nu Ọ̀nà Tẹmpili. +Bí Peteru ti ń bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Johanu wà lọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn alufaa ati olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn Sadusi bá dé. +ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo yín ati gbogbo eniyan Israẹli pé, ọkunrin yìí dúró níwájú yín pẹlu ara líle nítorí orúkọ Jesu Kristi ará Nasarẹti, ẹni tí ẹ kàn mọ́ agbelebu, tí Ọlọrun jí dìde kúrò ninu òkú. +Jesu yìí ni ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,tí ó wá di òkúta pataki igun-ilé.’ +Kò sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; bẹ́ẹ̀ ni kò sí orúkọ mìíràn tí a fi fún eniyan lábẹ́ ọ̀run nípa èyí tí a lè fi gba eniyan là.” +Nígbà tí wọ́n rí ìgboyà Peteru ati ti Johanu, tí wọ́n wòye pé wọn kò mọ ìwé àtipé òpè eniyan ni wọ́n, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ṣe akiyesi wọn pé wọ́n ti wà pẹlu Jesu. +Wọ́n wo ọkunrin tí wọ́n mú lára dá tí ó dúró lọ́dọ̀ wọn, wọn kò sì mọ ohun tí wọn yóo sọ. +Wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìgbìmọ̀. Àwọn ìgbìmọ̀ wá ń bi ara wọn pé, +“Kí ni a óo ṣe sí àwọn ọkunrin wọnyi o? Nítorí ó hàn lónìí sí gbogbo àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu pé wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abàmì. A kò sì lè wí pé èyí kò rí bẹ́ẹ̀. +Ṣugbọn kí ó má baà tún máa tàn kálẹ̀ sí i láàrin àwọn eniyan, ẹ jẹ́ kí á kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ dárúkọ Jesu fún ẹnikẹ́ni mọ́.” +Àwọn ìgbìmọ̀ bá tún pè wọ́n wọlé, wọ́n pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tún dárúkọ Jesu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ tún fi orúkọ Jesu kọ́ àwọn eniyan mọ́. +Ṣugbọn Peteru ati Johanu dá wọn lóhùn pé, “Èwo ni ó tọ́ níwájú Ọlọrun: kí á gbọ́ràn si yín lẹ́nu ni, tabi kí á gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu? Ẹ̀yin náà ẹ dà á rò. +Inú bí wọn nítorí wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan pé àwọn òkú yóo jí dìde. Wọ́n fi ajinde ti Jesu ṣe àpẹẹrẹ. +Ní tiwa, a kò lè ṣe aláìsọ ohun tí a ti rí ati ohun tí a ti gbọ́.” +Lẹ́yìn tí wọ́n tún halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n dá wọn sílẹ̀, nítorí wọn kò rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi jẹ wọ́n níyà, nítorí àwọn eniyan. Gbogbo eniyan ni wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọrun fún ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. +Ọkunrin tí wọn ṣe iṣẹ́ abàmì ìmúláradá yìí lára rẹ̀ ju ẹni ogoji ọdún lọ. +Nígbà tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ wọn, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà sọ fún wọn. +Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n jọ ké pe Ọlọrun pé, “Oluwa, ìwọ tí ó dá ọ̀run ati ayé ati òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn, +ìwọ tí ó sọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ láti ẹnu baba ńlá wa, Dafidi, ọmọ rẹ pé, ‘Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń di rìkíṣí,tí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè ń gbèrò asán? +Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,àwọn ìjòyè fohùn ṣọ̀kan,láti dìtẹ̀ sí Oluwa ati sí Mesaya rẹ̀.’ +Nítorí òdodo ni pé Hẹrọdu ati Pọntiu Pilatu pẹlu àwọn tí kì í ṣe Juu ati àwọn eniyan Israẹli péjọpọ̀ ní ìlú yìí, wọ́n ṣe ohun tí ó lòdì sí ọmọ mímọ́ rẹ, Jesu tí o ti fi òróró yàn ní Mesaya, +àwọn ohun tí ọwọ́ rẹ ati ètò rẹ ti ṣe ìlànà rẹ̀ tẹ́lẹ̀. +Ǹjẹ́ nisinsinyii, Oluwa, ṣe akiyesi bí wọ́n ti ń halẹ̀, kí o sì fún àwọn iranṣẹ rẹ ní ìgboyà ní gbogbo ọ̀nà láti lè sọ ọ̀rọ̀ rẹ. +Wọ́n bá mú wọn, wọ́n tì wọ́n mọ́lé títí di ọjọ́ keji, nítorí ilẹ̀ ti ṣú. +Kí o wá na ọwọ́ rẹ kí o ṣe ìwòsàn, ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu nípa orúkọ Jesu ọmọ mímọ́ rẹ.” +Bí wọ́n ti ń gbadura, ibi tí wọ́n péjọ sí mì tìtì, gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n bá ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. +Ọkàn kan ati ẹ̀mí kan ni gbogbo àwùjọ àwọn onigbagbọ ní. Kò sí ẹnìkan ninu wọn tí ó dá àwọn nǹkan tirẹ̀ yà sọ́tọ̀, wọ́n jọ ní gbogbo nǹkan papọ̀ ni. +Àwọn aposteli ń fi ẹ̀rí wọn hàn pẹlu agbára ńlá nípa ajinde Jesu Oluwa. Gbogbo àwọn eniyan sì ń bọlá fún wọn. +Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ṣe aláìní ohun kan láàrin wọn. Àwọn tí ó ní ilẹ̀ tabi ilé tà wọ́n, wọ́n mú owó tí wọ́n tà wọ́n wá, +wọ́n dà á sílẹ̀ níwájú àwọn aposteli kí wọ́n lè pín in fún àwọn tí ó bá ṣe aláìní. +Josẹfu, ọmọ ìdílé Lefi ará Kipru ẹni tí àwọn aposteli ń pè ní Banaba, (èyí ni “Ọmọ ìtùnú,”) +ní ilẹ̀ kan. Ó tà á, ó sì mú owó rẹ̀ wá fún àwọn aposteli. +Ṣugbọn ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́, iye wọn tó ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan. +Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, àwọn ìjòyè ati àwọn àgbààgbà ati àwọn amòfin péjọ ní Jerusalẹmu. +Anasi Olórí Alufaa ati Kayafa ati Johanu ati Alẹkisanderu ati àwọn ìdílé Olórí Alufaa wà níbẹ̀. +Wọ́n mú Peteru ati Johanu wá siwaju ìgbìmọ̀. Wọ́n wá bi wọ́n pé, “Irú agbára wo ni ẹ fi ṣe ohun tí ẹ ṣe yìí? Orúkọ ta ni ẹ lò?” +Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ wá fún Peteru ní agbára lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìjòyè láàrin àwọn eniyan ati ẹyin àgbààgbà, +bí ẹ bá ń wádìí lónìí nípa iṣẹ́ rere tí a ṣe fún ọkunrin aláìsàn yìí, bí ẹ bá fẹ́ mọ bí ara rẹ̀ ti ṣe dá, +A Mú Peteru ati Johanu Wá siwaju Ìgbìmọ̀ Àwọn Juu. +Ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania pẹlu Safira, iyawo rẹ̀, ta ilẹ̀ kan. +Ni òun náà bá ṣubú lulẹ̀ lẹsẹkẹsẹ níwájú Peteru, ó bá kú. Àwọn géńdé bá wọlé, wọ́n rí òkú rẹ̀. Wọ́n bá gbé e jáde, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀bá ọkọ rẹ̀. +Ẹ̀rù ńlá ba gbogbo ìjọ ati gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi. +Ọpọlọpọ iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu ni àwọn aposteli ṣe láàrin àwọn eniyan. Gbogbo wọn wà ní ìṣọ̀kan ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní ti Solomoni. +Kò sí ẹni tí ó láyà ninu àwọn ìyókù láti darapọ̀ mọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ wọn níyì lọ́dọ̀ àwọn eniyan. +Àwọn tí wọ́n gba Oluwa gbọ́ túbọ̀ ń darapọ̀ mọ́ wọn, lọkunrin ati lobinrin. +Nígbà tí ó yá, àwọn eniyan a máa gbé àwọn aláìsàn wá sí títì lórí ẹní ati lórí ibùsùn, pé kí òjìji Peteru lè ṣíji bò wọ́n nígbà tí ó bá ń kọjá. +Ọpọlọpọ àwọn eniyan wá láti agbègbè ìlú Jerusalẹmu, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn ati àwọn tí ẹ̀mí burúkú ń dà láàmú wá; a sì mú gbogbo wọn lára dá. +Nígbà náà ni ẹ̀tanú gba ọkàn Olórí Alufaa ati gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sadusi tí ó wà pẹlu rẹ̀. +Wọ́n bá mú àwọn aposteli, wọ́n tì wọ́n mọ́lé ninu ilé ẹ̀wọ̀n ìgboro ìlú. +Nígbà tí ó di òru, angẹli Oluwa ṣí ìlẹ̀kùn ilé-ẹ̀wọ̀n, ó sìn wọ́n jáde, ó sọ fún wọn pé, +Ọkunrin yìí yọ sílẹ̀ ninu owó tí wọ́n rí lórí rẹ̀, ó bá mú ìyókù wá siwaju àwọn aposteli. Iyawo rẹ̀ sì mọ̀ nípa rẹ̀. +“Ẹ lọ dúró ninu Tẹmpili kí ẹ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ ìyè yìí fún àwọn eniyan.” +Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n wọ inú Tẹmpili lọ nígbà tí ojúmọ́ mọ́, wọ́n bá ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́.Nígbà tí Olórí Alufaa dé pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó pe ìgbìmọ̀ ati gbogbo àwọn àgbààgbà láàrin àwọn ọmọ Israẹli jọ. Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí inú ẹ̀wọ̀n kí wọn lọ mú àwọn aposteli náà wá. +Nígbà tí àwọn tí wọ́n rán dé ilé-ẹ̀wọ̀n, wọn kò rí wọn níbẹ̀. Wọ́n bá pada lọ jíṣẹ́ pé, +“A fojú wa rí ilé-ẹ̀wọ̀n ní títì, a bá àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọ tí wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà. Ṣugbọn nígbà tí a ṣílẹ̀kùn, tí a wọ inú ilé, a kò rí ẹnìkan.” +Nígbà tí ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ ti Tẹmpili ati àwọn olórí alufaa gbọ́ ìròyìn yìí, ọkàn wọn dàrú; wọ́n ń ronú pé, irú kí ni eléyìí? +Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹnìkan bá dé, wọ́n sọ fún wọn pé, “Àwọn ọkunrin tí ẹ tì mọ́lé wà ninu Tẹmpili, tí wọn ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́.” +Nígbà náà ni ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ ati àwọn iranṣẹ lọ mú àwọn aposteli. Àwọn ẹ̀ṣọ́ náà kò fi ipá mú wọn, nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan kí àwọn eniyan má baà sọ wọ́n ní òkúta. +Wọ́n mú wọn wá siwaju ìgbìmọ̀. Olórí Alufaa wá bi wọ́n pé, +“Mo ṣebí a pàṣẹ fun yín pé kí ẹ má fi orúkọ yìí kọ́ ẹnikẹ́ni mọ́? Sibẹ gbogbo ará Jerusalẹmu ni ó ti gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ yín yìí. Ẹ wá tún di ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkunrin yìí lé wa lórí?” +Peteru pẹlu àwọn aposteli dáhùn pé, “A níláti gbọ́ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ. +Peteru bá bi í pé, “Anania, kí ló dé tí Satani fi gbà ọ́ lọ́kàn tí o fi ṣe èké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí o fi yọ sílẹ̀ ninu owó tí o rí lórí ilẹ̀ náà? +Jesu tí ẹ̀yin pa, tí ẹ kàn mọ́ igi, Ọlọrun àwọn baba wa jí i dìde. +Òun ni Ọlọrun fi ṣe aṣiwaju ati olùgbàlà, tí ó gbé sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, kí ó lè fi anfaani ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli. +Àwa gan-an ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí Ọlọrun fi fún àwọn tí ó gbọ́ràn sí i lẹ́nu ni ẹlẹ́rìí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi.” +Ọ̀rọ̀ yìí gún àwọn tí ó gbọ́ ọ lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ pa wọ́n. +Ṣugbọn Farisi kan ninu àwọn ìgbìmọ̀ dìde. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gamalieli, olùkọ́ nípa ti òfin ni, ó lókìkí láàrin gbogbo àwọn eniyan. Ó ní kí àwọn ọkunrin náà jáde fún ìgbà díẹ̀. +Ó wá sọ fún àwọn ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ṣọ́ra nípa ohun tí ẹ fẹ́ ṣe sí àwọn ọkunrin yìí. +Nítorí nígbà kan, Tudasi kan dìde. Ó ní òun jẹ́ eniyan ńlá kan. Ó kó àwọn eniyan bí irinwo (400) jọ. Nígbà tó yá wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká; gbogbo ọ̀tẹ̀ rẹ̀ sì jásí òfo. +Lẹ́yìn èyí, Judasi kan, ará Galili, dìde ní àkókò tí à ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀. Àwọn eniyan tẹ̀lé e. Ṣugbọn wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká. +To ò, mo sọ fun yín o! Ẹ gáfárà fún àwọn ọkunrin yìí; ẹ fi wọ́n sílẹ̀ o! Bí ète yìí tabi ohun tí wọn ń ṣe bá jẹ́ láti ọwọ́ eniyan, yóo parẹ́. +Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ láti ọwọ́ Ọlọrun ni, ẹ kò lè pa wọ́n run, ẹ óo kàn máa bá Ọlọrun jagun ni!” Àwọn ìgbìmọ̀ rí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. +Kí o tó ta ilẹ̀ náà, mo ṣebí tìrẹ ni? Nígbà tí o tà á tán, mo ṣebí o ní àṣẹ lórí owó tí o tà á? Kí ló dé tí o gbèrò irú nǹkan yìí? Kì í ṣe eniyan ni o ṣèké sí, Ọlọrun ni.” +Wọ́n bá pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n nà wọ́n, wọ́n kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fi orúkọ Jesu sọ̀rọ̀ mọ́. Wọ́n bá dá wọn sílẹ̀. +Wọ́n jáde kúrò níwájú ìgbìmọ̀, wọ́n ń yọ̀ nítorí a kà wọ́n yẹ kún àwọn tí a fi àbùkù kan nítorí orúkọ Jesu. +Lojoojumọ, ninu Tẹmpili ati láti ilé dé ilé, wọn kò dẹ́kun láti máa kọ́ eniyan ati láti máa waasu pé Jesu ni Mesaya. +Nígbà tí Anania gbọ́ gbolohun yìí, ó ṣubú lulẹ̀, ó kú. Ẹ̀rù ńlá sì ba gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́. +Àwọn géńdé bá dìde, wọ́n fi aṣọ wé e, wọ́n gbé e lọ sin. +Nígbà tí ó tó bíi wakati mẹta lẹ́yìn náà, iyawo Anania wọlé dé. Kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. +Peteru bi í pé, “Sọ fún mi, ṣé iye tí ẹ ta ilẹ̀ náà nìyí?”Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye tí a tà á ni.” +Peteru bá bi í pé, “Kí ló dé tí ẹ jọ fi ohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Oluwa wò? Wo ẹsẹ̀ àwọn tí wọ́n lọ sin ọkọ rẹ lẹ́nu ọ̀nà, wọn yóo gbé ìwọ náà jáde.” +Ìtàn Anania ati Safira. +Nígbà tí ó yá, tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn tí ó ń sọ èdè Giriki ati àwọn tí ó ń sọ èdè Heberu, nítorí wọ́n ń fojú fo àwọn opó àwọn tí ń sọ èdè Giriki dá, nígbà tí wọ́n bá ń pín àwọn nǹkan ní ojoojumọ. +Ṣugbọn wọn kò lè fèsì sí irú ọgbọ́n ati ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀. +Wọ́n bá rú àwọn eniyan nídìí, láti sọ pé, “A gbọ́ nígbà tí ó ń sọ ìsọkúsọ sí Mose ati sí Ọlọrun.” +Wọ́n rú àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà ati àwọn amòfin nídìí, ni wọ́n bá mú un, wọ́n fà á lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. +Wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí èké tí wọ́n sọ pé, “Ọkunrin yìí kò yé sọ̀rọ̀ lòdì sí Tẹmpili mímọ́ yìí ati sí òfin Mose. +Nítorí a gbọ́ nígbà tí ó sọ pé Jesu ti Nasarẹti yóo wó ilé yìí, yóo yí àwọn àṣà tí Mose fún wa pada.” +Gbogbo àwọn tí ó jókòó ní ìgbìmọ̀ tẹjú mọ́ ọn, wọ́n rí ojú rẹ̀ tí ó dàbí ojú angẹli. +Àwọn aposteli mejila bá pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yòókù jọ, wọ́n ní, “Kò yẹ kí á fi iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílẹ̀, kí á máa ṣe ètò oúnjẹ. +Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ wá ẹni meje láàrin yín, tí wọ́n ní orúkọ rere, tí wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ ati ọgbọ́n, kí á yàn wọ́n láti mójútó ètò yìí. +Àwa ní tiwa, a óo tẹra mọ́ adura gbígbà ati iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ ìyìn rere.” +Ọ̀rọ̀ yìí dára lójú gbogbo àwùjọ, wọ́n bá yan Stefanu. Stefanu yìí jẹ́ onigbagbọ tọkàntọkàn, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Wọ́n yan Filipi náà ati Prokoru ati Nikanọ ati Timoni ati Pamena ati Nikolausi ará Antioku tí ó ti gba ẹ̀sìn àwọn Juu. +Wọ́n kó wọn wá siwaju àwọn aposteli; wọ́n gbadura, wọ́n bá gbé ọwọ́ lé wọn lórí. +Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá ń gbilẹ̀. Iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní Jerusalẹmu. Pupọ ninu àwọn alufaa ni wọ́n sì di onigbagbọ. +Stefanu ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì ńlá láàrin àwọn eniyan nítorí pé ẹ̀bùn ati agbára Ọlọrun pọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. +Àwọn kan wá láti ilé ìpàdé kan tí à ń pè ní ti àwọn Olómìnira, ti àwọn ará Kurene ati àwọn ará Alẹkisandria; wọ́n tako Stefanu. Àwọn tí wọ́n wá láti Silisia ati láti Esia náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn. +A Yan Àwọn Olùrànlọ́wọ́ Meje. +Olórí Alufaa bá bi í pé, “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn náà rí?” +Ọlọrun yọ ọ́ kúrò ninu gbogbo ìpọ́njú tí ó rí. Nígbà tí ó yọ siwaju Farao, ọba Ijipti, Ọlọrun fún un lọ́gbọ́n, ó sì jẹ́ kí ó rí ojú àánú ọba Ijipti. Farao bá fi jẹ gomina lórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati lórí ààfin ọba. +Nígbà tí ó yá, ìyàn mú ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati ní ilẹ̀ Kenaani. Eléyìí mú ìṣòro pupọ wá. Àwọn eniyan wa kò bá rí oúnjẹ jẹ. +Nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé oúnjẹ wà ní Ijipti, ó kọ́kọ́ rán àwọn baba wa lọ. +Ní ẹẹkeji ni àwọn arakunrin rẹ̀ tó mọ ẹni tí Josẹfu jẹ́. A sì fi ìdílé Josẹfu han Farao. +Josẹfu bá ranṣẹ láti pe Jakọbu baba rẹ̀ wá ati gbogbo àwọn ẹbí rẹ̀. Wọ́n jẹ́ eniyan marunlelaadọrin (75). +Jakọbu bá lọ sí Ijipti. Níbẹ̀ ni ó kú sí, òun ati àwọn baba wa náà. +Wọ́n gbé òkú wọn lọ sí Ṣekemu, wọ́n sin wọ́n sinu ibojì tí Abrahamu fowó rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori ní Ṣekemu. +“Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò tí ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún Abrahamu yóo ṣẹ, àwọn eniyan náà wá túbọ̀ ń pọ̀ níye ní Ijipti. +Nígbà tó yá, ọba mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ijipti. +Ọba yìí bá fi ọgbọ́n àrékérekè bá orílẹ̀-èdè wa lò. Ó dá àwọn baba wa lóró, ó mú kí wọ́n máa sọ ọmọ nù, kí wọ́n baà lè kú. +Stefanu bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin ati baba mi, ẹ gbọ́ ohun tí mo ní sọ. Ọlọrun Ológo farahàn fún baba wa, Abrahamu, nígbà tí ó ṣì wà ní ilẹ̀ Mesopotamia, kí ó tó wá máa gbé ilẹ̀ Kenaani. +Ní àkókò yìí ni a bí Mose. Ó dára lọ́mọ pupọ. Àwọn òbí rẹ̀ tọ́ ọ fún oṣù mẹta ninu ilé baba rẹ̀ +Nígbà tí wọ́n sọ ọ́ nù, ni ọmọ Farao, obinrin, bá tọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ti ara rẹ̀. +Gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Ijipti ni wọ́n fi kọ́ Mose. Ati ọ̀rọ̀ sísọ, ati iṣẹ́ ṣíṣe kò sí èyí tí kò mọ̀ ọ́n ṣe. +“Nígbà tí Mose di ẹni ogoji ọdún, ó pinnu pé òun yóo lọ bẹ àwọn ará òun, àwọn ọmọ Israẹli, wò. +Ó bá rí ọ̀kan ninu àwọn ará rẹ̀ tí ará Ijipti ń jẹ níyà. Ó bá lọ gbà á sílẹ̀. Ó gbẹ̀san ìyà tí wọ́n ti fi jẹ ẹ́, ó lu ará Ijipti náà pa. +Ó rò pé yóo yé àwọn arakunrin òun pé Ọlọrun yóo ti ọwọ́ òun fún wọn ní òmìnira. Ṣugbọn kò yé wọn bẹ́ẹ̀. +Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó yọ sí àwọn kan tí wọn ń jà. Ó bá ní kí òun parí ìjà fún wọn. Ó ní, ‘Ẹ̀yin ará, arakunrin ara yín ni ẹ̀ ń ṣe. Kí ló dé tí ẹ̀ ń lu ara yín?’ +Ẹni tí ó jẹ̀bi tì í sẹ́yìn, ó ní, ‘Ta ni fi ọ́ ṣe olórí ati onídàájọ́ lórí wa? +Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ti ṣe pa ará Ijipti lánàá ni?’ +Nígbà tí Mose gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sálọ. Ó ń lọ gbé ilẹ̀ Midiani. Ó bí ọmọ meji níbẹ̀. +Ó sọ fún un pé, ‘Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ, láàrin àwọn ẹbí rẹ, kí o lọ sí ilẹ̀ tí èmi yóo fihàn ọ́.’ +“Lẹ́yìn ogoji ọdún, angẹli kán yọ sí i ninu ìgbẹ́ tí ń jóná ní aṣálẹ̀ lẹ́bàá òkè Sinai. +Nígbà tí Mose rí ìran náà, ẹnu yà á. Nígbà tí ó súnmọ́ ọn pé kí òun wò ó fínnífínní, ó gbọ́ ohùn Oluwa tí ó sọ pé, +‘Èmi ni Ọlọrun àwọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati ti Jakọbu.’ Mose bá bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n. Kò tó ẹni tí í wò ó. +Oluwa tún sọ fún un pé, ‘Bọ́ sálúbàtà tí ó wà lẹ́sẹ̀ rẹ, nítorí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí. +Mo ti rí gbogbo ìrora tí àwọn eniyan mi ń jẹ ní Ijipti. Mo ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì ṣetán láti yọ wọ́n. Ó yá nisinsinyii. N óo rán ọ lọ sí Ijipti.’ +“Mose yìí kan náà, tí wọ́n kọ̀, tí wọ́n sọ fún pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ ṣe olórí ati onídàájọ́?’ Òun ni Ọlọrun rán angẹli sí, tí ó farahàn án ninu ìgbẹ́ tí ń jó, láti jẹ́ olórí ati olùdáǹdè. +Mose yìí ni aṣaaju wọn, tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti ní Òkun Pupa ati ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún. +Mose yìí ni ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọrun yóo gbé wolii kan bí èmi dìde fun yín láàrin àwọn arakunrin yín.’ +Mose náà ni ó bá angẹli sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai nígbà tí wọ́n wà ninu àwùjọ ní aṣálẹ̀, tí ó tún bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀. Òun ni ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó fi fún wa. +“Ṣugbọn àwọn baba wa kò fẹ́ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́. Wọ́n tì í kúrò lọ́dọ̀ wọn; ọkàn wọn tún pada sí Ijipti. +Ó bá jáde kúrò ní ilẹ̀ Kalidea láti máa gbé Kenaani. Nígbà tí baba rẹ̀ kú, ó kúrò níbẹ̀ láti wá máa gbé ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀ ń gbé nisinsinyii. +Wọ́n sọ fún Aaroni pé, ‘Ṣe oriṣa fún wa kí á rí ohun máa bọ, kí ó máa tọ́ wa sí ọ̀nà. A kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti.’ +Wọ́n bá ṣe ère ọmọ mààlúù kan ní àkókò náà, wọ́n rúbọ sí i. Wọ́n bá ń ṣe àríyá lórí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe. +Ọlọrun bá pada lẹ́yìn wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ láti máa sin ìràwọ̀ ojú ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii pé, ‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli,ǹjẹ́ ẹ mú ẹran wá fi rúbọ sí mi fún ogoji ọdún ní aṣálẹ̀? +Ṣebí àtíbàbà Moleki ni ẹ gbé rù,ati ìràwọ̀ Refani oriṣa yín,àwọn ère tí ẹ ṣe láti máa foríbalẹ̀ fún?N óo le yín lọ sí ìgbèkùn, ẹ óo kọjá Babiloni.’ +“Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí kan ní aṣálẹ̀. Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀, ó sì pàṣẹ fún un pé kí ó ṣe àgọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí òun ti fihàn án tẹ́lẹ̀. +Àwọn baba wa tí wọ́n tẹ̀lé Joṣua gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun lé kúrò níwájú wọn, lẹ́yìn náà wọ́n gbé àgọ́ náà wá. Àgọ́ yìí sì wà pẹlu wa títí di àkókò Dafidi. +Dafidi bá ojurere Ọlọrun pàdé; ó wá bèèrè pé kí Ọlọrun jẹ́ kí òun kọ́ ilé fún òun, Ọlọrun Jakọbu. +Ṣugbọn Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un. +“Bẹ́ẹ̀ ni Ọba tí ó ga jùlọ kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́. Gẹ́gẹ́ bí wolii nì ti sọ: +‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni tìmùtìmù ìtìsẹ̀ mi. Irú ilé wo ni ẹ̀ báà kọ́ fún mi?Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí.Níbo ni ẹ̀ báà palẹ̀ mọ́ fún mi pé kí n ti máa sinmi? +Ní àkókò náà, Ọlọrun kò fún un ní ogún ninu ilẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ ṣe ẹsẹ̀ bàtà kan, kò ní níbẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ṣe ìlérí láti fún òun ati ọmọ rẹ̀ tí yóo gbẹ̀yìn rẹ̀ ní ilẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní ọmọ ní àkókò náà. +Ṣebí èmi ni mo fọwọ́ mi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi?’ +“Ẹ̀yin olóríkunkun, ọlọ́kàn líle, elétí dídi wọnyi! Nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń tako Ẹ̀mí Mímọ́. Bí àwọn baba yín ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà rí. +Èwo ninu àwọn wolii ni àwọn Baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọ́n pa àwọn tí wọ́n sọtẹ́lẹ̀ pé Ẹni olódodo yóo dé. Ní àkókò yìí ẹ wá dìtẹ̀ sí i, ẹ ṣe ikú pa á. +Ẹ̀yin yìí ni ẹ gba òfin Ọlọrun láti ọwọ́ àwọn angẹli, ṣugbọn ẹ kò pa òfin náà mọ́.” +Nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ó gún wọn lọ́kàn. Wọ́n bá pòṣé sí i. +Ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ gbé Stefanu, ó tẹ ojú mọ́ òkè ọ̀run, ó rí ògo Ọlọrun, ó tún rí Jesu tí ó dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun. +Ó bá dáhùn pé, “Ẹ wò ó, mo rí ojú ọ̀run tí ó pínyà. Mo wá rí Ọmọ-Eniyan tí ó dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun.” +Ni wọ́n bá kígbe, wọ́n fi ọwọ́ di etí, gbogbo wọ́n rọ́ lù ú; +wọ́n fà á jáde lọ sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n bá ń sọ ọ́ ní òkúta. Àwọn ẹlẹ́rìí fi ẹ̀wù wọn lélẹ̀ níwájú ọdọmọkunrin kan tí à ń pè ní Saulu. +Bí wọ́n ti ń sọ òkúta lu Stefanu, ó ké pe Jesu Oluwa, ó ní, “Oluwa Jesu, gba ẹ̀mí mi.” +Ọlọrun sọ fún un pé, ‘Àwọn ọmọ rẹ yóo jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ àjèjì. Àwọn eniyan ibẹ̀ yóo lò wọ́n bí ẹrú, wọn óo pọ́n wọn lójú fún irinwo (400) ọdún. +Ni ó bá kúnlẹ̀, ó kígbe, ó ní, “Oluwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kú. +Ṣugbọn orílẹ̀-èdè tí ó lò wọ́n bí ẹrú ni Èmi yóo dá lẹ́jọ́. Lẹ́yìn náà wọn yóo jáde kúrò ní ilẹ̀ àjèjì náà, wọn óo sì sìn mí ní ilẹ̀ yìí.’ +Ọlọrun wá bá a dá majẹmu, ó fi ilà kíkọ ṣe àmì majẹmu náà. Nígbà tí ó bí Isaaki, ó kọ ọ́ nílà ní ọjọ́ kẹjọ. Isaaki bí Jakọbu. Jakọbu bí àwọn baba-ńlá wa mejila. +“Àwọn baba-ńlá wa jowú Josẹfu, wọ́n tà á lẹ́rú sí ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. +Ọ̀rọ̀ Tí Stefanu Sọ. +Saulu bá wọn lọ́wọ́ sí ikú rẹ̀.Láti ọjọ́ náà ni inúnibíni ńlá ti bẹ̀rẹ̀ sí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn onigbagbọ bá túká lọ sí gbogbo agbègbè Judia ati Samaria. Àwọn aposteli nìkan ni kò kúrò ní ìlú. +Gbogbo eniyan ló kà á kún; ati àwọn eniyan yẹpẹrẹ ati àwọn eniyan pataki wọn. Wọ́n ní, “Eléyìí ní agbára Ọlọrun tí à ń pè ní ‘Agbára ńlá.’ ” +Tẹ́lẹ̀ rí òun ni àwọn eniyan kà kún, tí idán tí ó ń pa ń yà wọ́n lẹ́nu. +Ṣugbọn nígbà tí wọ́n gba ìyìn rere tí Filipi waasu nípa ìjọba Ọlọrun ati orúkọ Jesu Kristi gbọ́, tọkunrin tobinrin wọn ṣe ìrìbọmi. +Simoni náà gbàgbọ́, ó ṣe ìrìbọmi, ni ó bá fara mọ́ Filipi. Nígbà tí ó rí iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu ńlá tí ó ń ṣe, ẹnu yà á. +Àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu gbọ́ bí àwọn ará Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Wọ́n bá rán Peteru ati Johanu sí wọn. +Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n gbadura fún wọn kí wọ́n lè gba Ẹ̀mí Mímọ́, +nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ì tíì bà lé ẹnikẹ́ni ninu wọn. Ìrìbọmi ní orúkọ Oluwa Jesu nìkan ni wọ́n ṣe. +Lẹ́yìn tí Peteru ati Johanu ti gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n bá gba Ẹ̀mí Mímọ́. +Nígbà tí Simoni rí i pé ọwọ́ tí àwọn aposteli gbé lé wọn ni ó mú kí wọ́n rí Ẹ̀mí gbà, ó fi owó lọ̀ wọ́n. +Ó ní, “Ẹ fún mi ní irú àṣẹ yìí kí ẹni tí mo bá gbé ọwọ́ lé, lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.” +Àwọn olùfọkànsìn sin òkú Stefanu, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ pupọ lórí rẹ̀. +Ṣugbọn Peteru sọ fún un pé, “Ìwọ ati owó rẹ yóo ṣègbé! O rò pé o lè fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọrun. +O kò ní ipa tabi ìpín ninu ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ọkàn rẹ kò tọ́ níwájú Ọlọrun. +Nítorí náà, ronupiwada kúrò ninu ohun burúkú yìí, kí o tún bẹ Oluwa kí ó dárí èrò ọkàn rẹ yìí jì ọ́. +Nítorí mo wòye pé ẹ̀tanú ti gbà ọ́ lọ́kàn, àtipé aiṣododo ti dè ọ́ lẹ́wọ̀n.” +Simoni dá Peteru lóhùn pé, “Ẹ gbadura sí Oluwa fún mi kí ohunkohun tí ẹ wí má ṣẹlẹ̀ sí mi.” +Lẹ́yìn tí Peteru ati Johanu ti jẹ́rìí tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Oluwa tán, wọ́n pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n ń waasu ìyìn rere ní ọpọlọpọ àwọn abúlé ilẹ̀ Samaria bí wọ́n ti ń pada lọ. +Angẹli Oluwa sọ fún Filipi pé, “Dìde kí o lọ sí apá gúsù, ní ọ̀nà tí ó lọ láti Jerusalẹmu sí Gasa.” (Aṣálẹ̀ ni ọ̀nà yìí gbà lọ.) +Ni Filipi bá dìde lọ. Ó bá rí ọkunrin ará Etiopia kan. Ó jẹ́ ìwẹ̀fà onípò gíga kan lábẹ́ Kandake, ọbabinrin Etiopia. Òun ni akápò ìjọba. Ó ti lọ ṣe ìsìn ní Jerusalẹmu, +ó wá ń pada lọ sílé. Ó jókòó ninu ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ó ń ka ìwé wolii Aisaya. +Ẹ̀mí sọ fún Filipi pé, “Lọ síbi ọkọ nnì kí o súnmọ́ ọn.” +Ṣugbọn Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ rú. Ó ń wọ ojúlé kiri, ó ń fa tọkunrin tobinrin jáde, lọ sẹ́wọ̀n. +Nígbà tí Filipi sáré, tí ó súnmọ́ ọn, ó gbọ́ tí ó ń ka ìwé wolii Aisaya. Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ ohun tí ò ń kà yé ọ?” +Ó dáhùn pé, “Ó ṣe lè yé mi láìjẹ́ pé ẹnìkan bá ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi?” Ó bá bẹ Filipi pé kí ó gòkè wọ inú ọkọ̀, kí ó jókòó ti òun. +Apá ibi tí ó ń kà nìyí:“Bí aguntan tí a mú lọ sí ilé ìpẹran,tí à ń fà níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,kò fọhùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ya ẹnu rẹ̀. +A rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. A kò ṣe ẹ̀tọ́ nípa ọ̀ràn rẹ̀.Ẹnikẹ́ni kò ní lè sọ nípa ìran rẹ̀.Nítorí a pa á run kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.” +Ìwẹ̀fà náà sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́, ọ̀rọ̀ ta ni wolii Ọlọrun yìí ń sọ, ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ni tabi ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn?” +Filipi bá tẹnu bọ ọ̀rọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ láti ibi àkọsílẹ̀ yìí, ó waasu ìyìn rere Jesu fún un. +Bí wọn tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé odò kan. Ìwẹ̀fà náà sọ pé, “Wo omi. Kí ló dé tí o ò fi kúkú rì mí bọmi?” [ +Filipi sọ fún un pé, “Bí o bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ẹ̀tọ́ ni.” Ó dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu Kristi.”] +Ìwẹ̀fà náà bá pàṣẹ pé kí ọkọ̀ dúró. Òun ati Filipi bá sọ̀kalẹ̀, wọ́n lọ sinu odò, Filipi bá rì í bọmi. +Nígbà tí wọ́n jáde kúrò ninu odò. Ẹ̀mí Oluwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà náà kò sì rí i mọ́. Ó bá ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ pẹlu ayọ̀. +Àwọn tí wọ́n túká bá ń lọ káàkiri, wọ́n ń waasu ọ̀rọ̀ náà. +Ní Asotu ni a tún ti rí Filipi. Ó ń waasu ní gbogbo àwọn ìlú tí ó gbà kọjá títí ó fi dé Kesaria. +Filipi lọ sí ìlú Samaria kan, ó waasu fún wọn nípa Kristi. +Àwọn eniyan ṣù bo Filipi kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, wọ́n sì ń rí iṣẹ́ abàmì tí ó ń ṣe. +Nítorí àwọn ẹ̀mí burúkú ń lọgun bí wọ́n ti ń jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan. Bẹ́ẹ̀ ni a mú ọpọlọpọ àwọn arọ ati àwọn tí wọ́n ní àbùkù ara lára dá. +Inú àwọn eniyan dùn pupọ ní ìlú náà. +Ọkunrin kán wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni, tí ó ti máa ń pidán ní ìlú náà. Èyí jẹ́ ìyanu fún àwọn ará Samaria, wọ́n ní ẹni ńlá ni ọkunrin náà. +Saulu Ṣe Inúnibíni Sí Ìjọ Kristi. +Ní gbogbo àkókò yìí, Saulu ń fi ikú dẹ́rùba àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Oluwa. Ó lọ sọ́dọ̀ Olórí Alufaa, +Ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kan wà ní Damasku tí ń jẹ́ Anania. Oluwa pè é ní ojú ìran, ó ní, “Anania!”Anania bá dáhùn pé, “Èmi nìyí, Oluwa.” +Oluwa bá sọ fún un pé, “Dìde. Lọ sí títì tí à ń pè ní ‘Títì títọ́,’ ní ilé Judasi kí o bèèrè ẹni tí ó ń jẹ́ Saulu, ará Tasu. O óo bá a ní ibi tí ó gbé ń gbadura. +Ní ojú ìran, ó rí ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania, tí ó wọlé tọ̀ ọ́ lọ, tí ó fi ọwọ́ bà á lójú kí ó lè tún ríran.” +Anania dáhùn pé, “Oluwa, mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọkunrin yìí lẹ́nu ọpọlọpọ eniyan: oríṣìíríṣìí ibi ni ó ti ṣe sí àwọn eniyan mímọ́ rẹ ní Jerusalẹmu. +Wíwá tí ó tún wá síhìn-ín, ó wá pẹlu àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa láti de gbogbo àwọn tí ó ń pe orúkọ rẹ ni.” +Oluwa sọ fún un pé, “Lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí mo ti yàn án láti mú orúkọ mi lọ siwaju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ati àwọn ọba wọn ati àwọn ọmọ Israẹli. +N óo fi oríṣìíríṣìí ìyà tí ó níláti jẹ nítorí orúkọ mi hàn án.” +Anania bá lọ, ó wọ inú ilé náà, ó fi ọwọ́ kan Saulu. Ó ní, “Saulu arakunrin mi, Oluwa ni ó rán mi sí ọ. Jesu tí ó farahàn ọ́ ní ojú ọ̀nà tí o gbà wá, ni ó rán mi wá, kí o lè tún ríran, kí o sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.” +Lẹsẹkẹsẹ nǹkankan bọ́ sílẹ̀ lójú rẹ̀ bí ìpẹ́pẹ́, ó sì tún ríran. Ó dìde, ó bá gba ìrìbọmi. +Ó bá jẹun, ara rẹ̀ bá tún mókun. Ó wà pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó wà ní Damasku fún ọjọ́ díẹ̀. +ó gba ìwé lọ́dọ̀ rẹ̀ láti lọ sí àwọn ilé ìpàdé tí ó wà ní Damasku. Ìwé yìí fún un ní àṣẹ pé bí ó bá rí àwọn tí ń tẹ̀lé ọ̀nà ẹ̀sìn yìí, ìbáà ṣe ọkunrin ìbáà ṣe obinrin, kí ó dè wọ́n, kí ó sì fà wọ́n wá sí Jerusalẹmu. +Láì jáfara ó bẹ̀rẹ̀ sí waasu ninu ilé ìpàdé àwọn Juu pé Jesu ni Ọmọ Ọlọrun. +Ẹnu ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n ní “Ará ibí yìí kọ́ ni ó ń pa àwọn tí ó ń pe orúkọ yìí ní Jerusalẹmu, tí ó tún wá síhìn-ín láti fi ẹ̀wọ̀n dè wọ́n, tí ó fẹ́ fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa?” +Ṣugbọn ńṣe ni Saulu túbọ̀ ń lágbára sí i. Àwọn Juu tí ó ń gbé Damasku kò mọ ohun tí wọ́n le wí mọ́, nítorí ó fi ẹ̀rí hàn pé Jesu ni Mesaya. +Bí ọjọ́ tí ń gorí ọjọ́ àwọn Juu gbèrò pọ̀ bí wọn yóo ti ṣe pa á. +Ṣugbọn Saulu gbọ́ nípa ète wọn. Wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu odi ìlú tọ̀sán-tòru kí wọ́n baà lè pa á. +Ṣugbọn ní alẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e sinu apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí odi ìlú. +Nígbà tí Saulu dé Jerusalẹmu, ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn ẹ̀rù rẹ̀ ń bà wọ́n; wọn kò gbàgbọ́ pé ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. +Ṣugbọn Banaba mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó ròyìn fún wọn bí ó ti rí Oluwa lọ́nà, bí Oluwa ti bá a sọ̀r��̣, ati bí ó ti fi ìgboyà waasu lórúkọ Jesu ní Damasku. +Ó bá ń bá wọn gbé ní Jerusalẹmu, ó ń wọlé, ó ń jáde, ó ń fi ìgboyà waasu lórúkọ Oluwa, +ó ń bá àwọn Juu tí ó ń sọ èdè Giriki jiyàn. Ṣugbọn wọ́n gbèrò láti pa á. +Bí ó ti ń lọ lọ́nà, tí ó súnmọ́ Damasku, iná kan mọ́lẹ̀ yí i ká lójijì; +Nígbà tí àwọn onigbagbọ mọ̀, wọ́n sìn ín lọ sí Kesaria, wọ́n fi ranṣẹ sí Tasu. +Gbogbo ìjọ ní Judia, ati Galili, ati Samaria wà ní alaafia, wọ́n sì fìdí múlẹ̀. Wọ́n ń gbé ìgbé-ayé wọn pẹlu ìbẹ̀rù Oluwa, wọ́n sì ń pọ̀ sí i nípa ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. +Bí Peteru tí ń lọ káàkiri láti ibìkan dé ibi keji, ó dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Ọlọrun tí wọn ń gbé ìlú Lida. +Ó rí ọkunrin kan níbẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Iniasi tí ó ti wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn fún ọdún mẹjọ; kò lè dá ara gbé nílẹ̀. +Peteru bá sọ fún un pé, “Iniasi, Jesu Kristi wò ọ́ sàn. Dìde, kà ẹní rẹ.” Lẹsẹkẹsẹ, ó bá dìde. +Gbogbo àwọn tí ó ń gbé Lida ati Ṣaroni rí i, wọ́n bá yipada, wọ́n di onigbagbọ. +Ọmọ-ẹ̀yìn kan wà ní Jọpa, tí ó jẹ́ obinrin, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tabita, tabi Dọkasi ní èdè Giriki. (Ìtumọ̀ rẹ̀ ni èkùlù.) Obinrin yìí jẹ́ ẹnìkan tíí máa ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ rere, ó sì láàánú pupọ. +Ní àkókò yìí ó wá ṣàìsàn, ó sì kú. Wọ́n bá wẹ̀ ẹ́, wọ́n tẹ́ ẹ sí yàrá lókè ní ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan. +Lida kò jìnnà sí Jọpa, nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Jọpa ti gbọ́ pé Peteru wà ní Lida. Wọ́n bá rán ọkunrin meji lọ sibẹ, kí wọ́n lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó má jáfara kí ó yára wá sọ́dọ̀ wọn. +Peteru bá gbéra, ó tẹ̀lé wọn. Nígbà tí ó dé Jọpa, ó lọ sí iyàrá lókè. Gbogbo àwọn opó bá yí i ká, wọ́n ń sunkún, wọ́n ń fi àwọn ẹ̀wù ati aṣọ tí Dọkasi máa ń rán fún wọn nígbà tí ó wà láàyè han Peteru. +ó bá ṣubú lulẹ̀. Ó wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó bi í pé, “Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” +Peteru bá ti gbogbo wọn jáde, ó kúnlẹ̀, ó gbadura. Ó bá kọjú sí òkú náà, ó ní, “Tabita, dìde.” Ni Tabita bá lajú, ó rí Peteru, ó bá dìde jókòó. +Peteru bá fà á lọ́wọ́ dìde. Ó pe àwọn eniyan Ọlọrun ati àwọn opó, ó bá fa Dọkasi lé wọn lọ́wọ́ láàyè. +Ìròyìn yìí tàn ká gbogbo Jọpa, ọpọlọpọ sì gba Oluwa gbọ́. +Peteru dúró fún ọjọ́ pupọ ní Jọpa, ní ọ̀dọ̀ Simoni, tí ń ṣe òwò awọ. +Saulu bèèrè pé, “Ta ni ọ́, Oluwa?”Ẹni náà bá dáhùn pé, “Èmi ni Jesu, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí. +Dìde nisinsinyii, kí o wọ inú ìlú lọ. A óo sọ ohun tí o níláti ṣe fún ọ.” +Àwọn ọkunrin tí ó ń bá a rìn dúró. Wọn kò sọ ohunkohun. Wọ́n ń gbọ́ ohùn eniyan, ṣugbọn wọn kò rí ẹnìkankan. +Saulu bá dìde nílẹ̀, ó la ojú sílẹ̀ ṣugbọn kò ríran. Wọ́n bá fà á lọ́wọ́ lọ sí Damasku. +Fún ọjọ́ mẹta, kò ríran, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu. +Saulu di Onigbagbọ. +Ìran tí Amosi, ọ̀kan ninu àwọn darandaran Tekoa, rí nípa Israẹli nìyí, nígbà ayé Usaya, ọba Juda, ati Jeroboamu, ọmọ Jehoaṣi, ọba Israẹli, ní ọdún meji ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ tí ilẹ̀ fi mì jìgìjìgì. +Nítorí náà n óo sọ iná sí orí odi ìlú Tire, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun.” +OLUWA ní: “Àwọn ará Edomu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n dojú idà kọ arakunrin wọn, láìṣàánú wọn, wọ́n bínú kọjá ààlà, títí lae sì ni ìrúnú wọn. +Nítorí náà, n óo rán iná sí ìlú Temani, yóo sì jó ibi ààbò Bosira ní àjórun.” +OLUWA ní: “Àwọn ará Amoni ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; wọ́n fi ìwà wọ̀bìà bẹ́ inú àwọn aboyún ilẹ̀ Gileadi, láti gba ilẹ̀ kún ilẹ̀ wọn. +Nítorí náà, n óo sọ iná sí orí odi ìlú Raba, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun. Ariwo yóo sọ ní ọjọ́ ogun, omi òkun yóo ru sókè ní ọjọ́ ìjì; +ọba wọn ati àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo sì lọ sí ìgbèkùn.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +Amosi ní:“OLUWA bú ramúramù lórí Òkè Sioni,ó fọhùn ní Jerusalẹmu;àwọn pápá tútù rọ,ewéko tútù orí òkè Kamẹli sì rẹ̀.” +OLUWA ní, “Àwọn ará Damasku ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà. Wọ́n mú ohun èlò ìpakà onírin ṣómúṣómú, wọ́n fi pa àwọn ará Gileadi ní ìpa ìkà. +Nítorí náà, n óo sọ iná sí ààfin Hasaeli, yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi kanlẹ̀. +N óo fọ́ ìlẹ̀kùn odi ìlú Damasku. N óo sì pa gbogbo àw���n ará àfonífojì Afeni run. Wọn óo mú ọba Betedeni lọ sí ìgbèkùn; òun ati àwọn ará Siria yóo lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Kiri.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +Ó ní: “Àwọn ará Gasa ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí odidi orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n kó lẹ́rú, tí wọ́n lọ tà fún àwọn ará Edomu. +N óo sọ iná sí ìlú Gasa, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun. +N óo pa gbogbo àwọn ará Aṣidodu run ati ọba Aṣikeloni; n óo jẹ ìlú Ekironi níyà, àwọn ará Filistia yòókù yóo sì ṣègbé.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀. +Ó ní: “Àwọn ará Tire ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n kó odidi orílẹ̀-èdè kan lẹ́rú lọ tà fún àwọn ará Edomu. Wọn kò sì ranti majẹmu tí wọ́n bá àwọn arakunrin wọn dá. +Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí Ó yí Israẹli ká Siria. +OLUWA ní: “Àwọn ará Moabu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n sọná sí egungun ọba Edomu, wọ́n sun ún, ó jóná ráúráú. +Èmi fúnra mi ni mo mu yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, mo mu yín la aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún, kí ẹ lè gba ilẹ̀ àwọn ará Amori. +Mo yan àwọn kan ninu àwọn ọmọ yín ní wolii mi, mo sì yan àwọn mìíràn ninu wọn ní Nasiri. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +Ṣugbọn ẹ̀ ń mú kí àwọn Nasiri mu ọtí, ẹ sì ń dá àwọn wolii mi lẹ́kun, pé wọn kò gbọdọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́. +Wò ó, n óo tẹ̀ yín ní àtẹ̀rẹ́ ní ibùgbé yín, bí ìgbà tí ọkọ̀ kọjá lórí eniyan. +Ní ọjọ́ náà, àárẹ̀ yóo mú àwọn tí wọ́n lè sáré; ipá àwọn alágbára yóo pin, akikanju kò sì ní lè gba ara rẹ̀ sílẹ̀. +Tafàtafà kò ní lè dúró, ẹni tí ó lè sáré kò ní lè sá àsálà; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣin kò ní lè gba ara wọn kalẹ̀. +Ìhòòhò ni àwọn akọni láàrin àwọn ọmọ ogun yóo sálọ ní ọjọ́ náà.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +Nítorí náà, n óo sọ iná sí Moabu, yóo sì jó àwọn ibi ààbò Kerioti ní àjórun. Ninu ariwo ogun ati ti fèrè ni Moabu yóo parun sí, +n óo sì pa ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ run.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +Ó ní: “Àwọn ará Juda ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n ti kọ òfin èmi OLUWA sílẹ̀, wọn kò sì rìn ní ìlànà mi. Àwọn oriṣa irọ́ tí àwọn baba wọn ń bọ, ti ṣì wọ́n lọ́nà. +Nítorí náà, n óo sọ iná sí Juda, yóo sì jó àwọn ibi ààbò Jerusalẹmu ní àjórun.” +OLUWA ní: “Àwọn ará Israẹli ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí pé wọ́n ta olódodo nítorí fadaka, wọ́n sì ta aláìní nítorí bàtà ẹsẹ̀ meji. +Wọ́n rẹ́ àwọn talaka jẹ, wọ́n sì yí ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ po. Baba ati ọmọ ń bá ẹrubinrin kanṣoṣo lòpọ̀, wọ́n sì ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. +Wọ́n sùn káàkiri yí pẹpẹ inú ilé Ọlọrun wọn ká, lórí aṣọ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn onígbèsè wọn; wọ́n ń mu ọtí tí àwọn kan fi san owó ìtanràn. +“Bẹ́ẹ̀ sì ni èmi ni mo pa àwọn ará Amori run fún wọn, àwọn géńdé, tí wọ́n ga bí igi kedari, tí wọ́n sì lágbára bí igi oaku; mo run wọ́n tèsotèso, tigbòǹgbò-tigbòǹgbò. +Moabu. +Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ nípa yín, gbogbo ẹ̀yin tí a kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti: OLUWA ní, +“Àwọn eniyan wọnyi ń kó nǹkan tí wọ́n fi ipá ati ìdigunjalè gbà sí ibi ààbò wọn, wọn kò mọ̀ bí à á tíí ṣe rere.” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ọ̀tá yóo yí ilẹ̀ náà po, wọn yóo wó ibi ààbò yín, wọn yóo sì kó ìṣúra tí ó wà ní àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.” +OLUWA ní: “Bí olùṣọ́-aguntan tií rí àjẹkù ẹsẹ̀ meji péré, tabi etí kan gbà kalẹ̀ lẹ́nu kinniun, ninu odidi àgbò, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria: díẹ̀ ninu wọn ni yóo là, àwọn tí wọn ń sùn lórí ibùsùn olówó iyebíye.” +OLUWA Ọlọrun, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ gbọ́, kí ẹ sì kìlọ̀ fún ìdílé Jakọbu. +Ní ọjọ́ tí n óo bá jẹ Israẹli níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, n óo jẹ pẹpẹ Bẹtẹli níyà, n óo kán àwọn ìwo tí ó wà lára pẹpẹ, wọn yóo sì bọ́ sílẹ̀. +N óo wó ilé tí ẹ kọ́ fún ìgbà òtútù ati èyí tí ẹ kọ́ fún ìgbà ooru; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ilé tí ẹ fi eyín erin kọ́ ati àwọn ilé ńláńlá yín yóo parẹ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +“Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀ láàrin gbogbo aráyé, nítorí náà, n óo jẹ yín níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. +“Ṣé eniyan meji lè jọ máa lọ sí ibìkan láìjẹ́ pé wọ́n ní àdéhùn? +“Ṣé kinniun a máa bú ninu igbó láìjẹ́ pé ó ti pa ẹran?“Àbí ọmọ kinniun a máa bú ninu ihò rẹ̀ láìṣe pé ọwọ́ rẹ̀ ti ba nǹkan? +“Ṣé tàkúté a máa mú ẹyẹ nílẹ̀, láìṣe pé eniyan ló dẹ ẹ́ sibẹ?“Àbí tàkúté a máa ta lásán láìṣe pé ó mú nǹkan? +“Ṣé eniyan lè fọn fèrè ogun láàrin ìlú kí àyà ará ìlú má já?“Àbí nǹkan ibi lè ṣẹlẹ̀ ní ìlú láìṣe pé OLUWA ni ó ṣe é? +“Dájúdájú OLUWA Ọlọrun kì í ṣe ohunkohun láì kọ́kọ́ fi han àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. +“Kinniun bú ramúramù, ta ni ẹ̀rù kò ní bà?“OLUWA Ọlọrun ti sọ̀rọ̀, ta ló gbọdọ̀ má sọ àsọtẹ́lẹ̀?” +Kéde fún àwọn ibi ààbò Asiria, ati àwọn ibi ààbò ilẹ̀ Ijipti, sọ pé: “Ẹ kó ara yín jọ sí orí àwọn òkè Samaria, kí ẹ sì wo rúdurùdu ati ìninilára tí ń ṣẹlẹ̀ ninu rẹ̀. +Iṣẹ́ Wolii. +Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin obinrin Samaria, ẹ̀yin tí ẹ sanra bíi mààlúù Baṣani, tí ẹ wà lórí òkè Samaria, tí ẹ̀ ń ni àwọn aláìní lára, tí ẹ̀ ń tẹ àwọn talaka ní àtẹ̀rẹ́, tí ẹ̀ ń wí fún àwọn ọkọ yín pé, “Ẹ gbé ọtí wá kí á mu.” +“Mo fi irú àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí ó jà ní Ijipti ba yín jà, mo fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin yín lójú ogun; mo kó ẹṣin yín lọ, mo mú kí òórùn àwọn tí wọ́n kú ninu àgọ́ yín wọ̀ yín nímú; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. +Mo pa àwọn kan ninu yín run bí mo ti pa Sodomu ati Gomora run, ẹ dàbí àjókù igi tí a yọ ninu iná; sibẹsibẹ, ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. +Nítorí náà, n óo jẹ yín níyà, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; nítorí irú ìyà tí n óo fi jẹ yín, ẹ múra sílẹ̀ de ìdájọ́ Ọlọrun yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli!” +Ẹ gbọ́! Ọlọrun ni ó dá òkè ńlá ati afẹ́fẹ́,tí ń fi èrò ọkàn rẹ̀ han eniyan,Ọlọrun ní ń sọ òwúrọ̀ di òru,tí sì ń rìn níbi gíga-gíga ayé;OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀! +OLUWA Ọlọrun ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, tí wọn óo fi ìwọ̀ fà yín lọ, gbogbo yín pátá ni wọn óo fi ìwọ̀ ẹja fà lọ, láì ku ẹnìkan. +Níbi tí odi ti ya ni wọn óo ti fà yín jáde, tí ẹ óo tò lẹ́sẹẹsẹ; a óo sì ko yín lọ sí Harimoni.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. +OLUWA ní, “Ẹ wá sí Bẹtẹli, kí ẹ wá máa dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀, kí ẹ sì wá fi ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ ní Giligali; ẹ máa mú ẹbọ yín wá ní àràárọ̀, ati ìdámẹ́wàá yín ní ọjọ́ kẹta kẹta. +Ẹ fi burẹdi tí ó ní ìwúkàrà rú ẹbọ ọpẹ́, ẹ kéde ẹbọ àtinúwá, kí ẹ sì fọ́nnu nípa rẹ̀; nítorí bẹ́ẹ̀ ni ẹ fẹ́ máa ṣe, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. +“Mo jẹ́ kí ìyàn mú ní gbogbo ìlú yín, kò sì sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ yín; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. +N kò jẹ́ kí òjò rọ̀ mọ́, nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹta; mò ń rọ òjò ní ìlú kan, kò sì dé ìlú keji; ó rọ̀ ní oko kan, ó dá ekeji sí, àwọn nǹkan ọ̀gbìn oko tí òjò kò rọ̀ sí sì rọ. +Nítorí náà, ìlú meji tabi mẹta ń wá omi lọ sí ẹyọ ìlú kan wọn kò sì rí tó nǹkan; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Mo jẹ́ kí nǹkan oko yín ati èso àjàrà yín rẹ̀ dànù, mo mú kí wọn rà; eṣú jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ ati igi olifi yín, sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. +Israẹli Kọ̀, Kò kẹ́kọ̀ọ́. +Ẹ fetí sí orin arò tí mò ń kọ le yín lórí, ẹ̀yin ìdílé Israẹli: +Wọ́n kórìíra ẹni tí ń bá ni wí lẹ́nu ibodè, wọ́n sì kórìíra ẹni tí ń sọ òtítọ́. +Ẹ̀ ń rẹ́ talaka jẹ, ẹ sì ń fi ipá gba ọkà wọn. Nítòótọ́, ẹ ti fi òkúta tí wọ́n dárà sí kọ́ ilé, ṣugbọn ẹ kò ní gbé inú wọn; ẹ ti ṣe ọgbà àjàrà dáradára, ṣugbọn ẹ kò ní mu ninu ọtí waini ibẹ̀. +Gbogbo ìwà àìdára yín ni mo mọ̀, mo sì mọ̀ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín ti tóbi tó, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fìyà jẹ olódodo, tí ẹ̀ ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ẹ sì ń du àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn lẹ́nu ibodè. +Nítorí náà, ẹni tí ó bá gbọ́n yóo dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní irú àkókò yìí, nítorí pé àkókò burúkú ni. +Ire ni kí ẹ máa wá, kì í ṣe ibi kí ẹ lè wà láàyè; nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun yóo wà pẹlu yín, bí ẹ ti jẹ́wọ́ rẹ̀. +Ẹ kórìíra ibi, kí ẹ sì fẹ́ ire, ẹ jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀ lẹ́nu ibodè yín; bóyá OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun yóo ṣàánú fún àwọn ọmọ ilé Josẹfu yòókù. +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọm��� ogun, àní OLUWA ní: “Ẹkún yóo wà ní gbogbo ìta gbangba, wọn yóo sì máa kọ ‘Háà! Háà!’ nígboro. Wọn yóo pe àwọn àgbẹ̀ pàápàá, ati àwọn tí wọn ń fi ẹkún sísun ṣe iṣẹ́ ṣe, láti wá sọkún àwọn tí wọ́n kú. +Wọn yóo sọkún ninu gbogbo ọgbà àjàrà yín, nítorí pé n óo gba ààrin yín kọjá. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń retí ọjọ́ OLUWA, ẹ gbé! Kí ni ẹ fẹ́ fi ọjọ́ OLUWA ṣe? Ọjọ́ òkùnkùn ni, kì í ṣe ọjọ́ ìmọ́lẹ̀. +Yóo dàbí ìgbà tí eniyan ń sálọ fún kinniun, tí ó pàdé ẹranko beari lọ́nà; tabi tí ó sá wọ ilé rẹ̀, tí ó fọwọ́ ti ògiri, tí ejò tún bù ú jẹ. +Israẹli, ọdọmọbinrin, ṣubú,kò ní lè dìde mọ́ lae.Ó di ìkọ̀sílẹ̀ ní ilẹ̀ rẹ̀,kò sì sí ẹni tí yóo gbé e dìde. +Ṣebí òkùnkùn ni ọjọ́ OLUWA, kì í ṣe ìmọ́lẹ̀! Ọjọ́ ìṣúdudu láìsí ìmọ́lẹ̀ ni. +Ọlọrun ní, “Mo kórìíra ọjọ́ àsè yín, n kò sì ní inú dídùn sí àwọn àpéjọ yín. +Bí ẹ tilẹ̀ rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ yín sí mi, n kò ní gbà wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní fojú rere wo ẹran àbọ́pa tí ẹ mú wá bí ọrẹ ẹbọ alaafia. +Ẹ dákẹ́ ariwo orin yín; n kò fẹ́ gbọ́ ohùn orin hapu yín mọ́. +Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí òtítọ́ máa ṣàn bí omi, kí òdodo sì máa ṣàn bí odò tí kò lè gbẹ. +“Ẹ gbọ́, ilé Israẹli, ǹjẹ́ ẹ mú ẹbọ ati ọrẹ wá fún mi ní gbogbo ogoji ọdún tí ẹ fi wà ninu aṣálẹ̀? +Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀ ń sin ère Sakuti, ọba yín, ati Kaiwani, oriṣa ìràwọ̀ yín, ati àwọn ère tí ẹ ṣe fún ara yín. +Nítorí náà, n óo ko yín lọ sí ìgbèkùn níwájú Damasku.” OLUWA, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọrun àwọn Ọmọ Ogun, ni ó sọ bẹ́ẹ̀. +OLUWA Ọlọrun ní: “Ninu ẹgbẹrun ọmọ ogun tí ìlú Israẹli kan bá rán jáde, ọgọrun-un péré ni yóo kù. Ninu ọgọrun-un tí ìlú mìíràn bá rán jáde, mẹ́wàá péré ni yóo kù.” +OLUWA ń sọ fún ilé Israẹli pé: “Ẹ wá mi, kí ẹ sì yè; +ẹ má lọ sí Bẹtẹli, ẹ má sì wọ Giligali, tabi kí ẹ kọjá lọ sí Beeriṣeba; nítorí a óo kó Giligali lọ sí oko ẹrú, Bẹtẹli yóo sì di asán.” +Ẹ wá OLUWA, kí ẹ sì yè; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo rọ̀jò iná sórí ilé Josẹfu, ati sí ìlú Bẹtẹli; kò sì ní sí ẹni tí yóo lè pa á. +Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ẹ̀bi fún aláre, tí ẹ sì tẹ òdodo mọ́lẹ̀. +Ẹni tí ó dá àwọn ìràwọ̀ Pileiadesi ati Orioni,tí ó sọ òkùnkùn biribiri di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,òun níí sọ ọ̀sán di òru;òun ni ó dá omi òkun sórí ilẹ̀,OLUWA ni orúkọ rẹ̀. +Òun ni ó ń mú ìparun wá sórí àwọn alágbára,kí ìparun lè bá ibi ààbò wọn. +Ìpè sí Ìrònúpìwàdà. +Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n wà ninu ìdẹ̀ra ní Sioni, ati àwọn tí wọn ń gbé orí òkè Samaria láìléwu, àwọn eniyan ńláńlá ní Israẹli, tí ó jẹ́ àkọ́kọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn tí àwọn eniyan gbójúlé. +Nígbà tí ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìsìnkú bá kó eegun òkú jáde, tí ó bá bi àwọn eniyan tí ó kù ninu ilé pé, “Ǹjẹ́ ó ku ẹnikẹ́ni mọ́?”Wọn yóo dá a lóhùn pé, “Rárá.”Nígbà náà ni olùdarí ìsìnkú yóo sọ pé, “Ẹ dákẹ́, ẹ ṣọ́ra, a kò gbọdọ̀ tilẹ̀ dárúkọ OLUWA.” +Wò ó! OLUWA pàṣẹ pé, a óo wó àwọn ilé ńlá, ati àwọn ilé kéékèèké lulẹ̀ patapata. +Ṣé ẹṣin a máa sáré lórí àpáta? Àbí eniyan a máa fi àjàgà mààlúù pa ilẹ̀ lórí òkun? Ṣugbọn ẹ ti sọ ẹ̀tọ́ di májèlé, ẹ sì ti sọ èso òdodo di ohun kíkorò. +Ẹ fọ́nnu pé ẹ̀yin ni ẹ ṣẹgun ìlú Lodebari, ẹ̀ ń wí pé: “Ṣebí agbára wa ni a fi gba ìlú Kanaimu.” +OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, n óo rán orílẹ̀-èdè kan láti pọn yín lójú, wọn yóo sì fìyà jẹ yín láti ibodè Hamati, títí dé odò Araba.” +Ẹ lọ wo ìlú Kane; ẹ ti ibẹ̀ lọ sí Hamati, ìlú ńlá nì, lẹ́yìn náà ẹ lọ sí ìlú Gati, ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ṣé wọ́n sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yín lọ ni? Tabi agbègbè wọn tóbi ju tiyín lọ? +Ẹ kò fẹ́ gbà pé ọjọ́ ibi ti súnmọ́ tòsí; ṣugbọn ẹ̀ ń ṣe nǹkan tí yóo mú kí ọjọ́ ẹ̀rù tètè dé. +Àwọn tí ń sùn sórí ibùsùn tí wọ́n fi eyín erin ṣe gbé! Àwọn tí wọ́n nà kalẹ̀ lórí ìrọ̀gbọ̀kú wọn, tí wọn ń jẹ ẹran ọ̀dọ́ aguntan, ati ti ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù láti inú agbo ẹran wọn! +Àwọn tí ń fi hapu kọ orin ìrégbè, tí wọ́n sì ń ṣe ohun èlò orin fún ara wọn bíi Dafidi. +Àwọn tí wọn ń fi abọ́ mu ọtí, tí wọn ń fi òróró olówó iyebíye para, ṣugbọn tí wọn kò bìkítà fún ìparun Josẹfu. +Nítorí náà, àwọn ni wọn yóo kọ́kọ́ lọ sí ìgbèkùn, gbogbo àsè ati ayẹyẹ àwọn tí wọn ń nà kalẹ̀ sórí ibùsùn yóo dópin. +OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra, ó ní: “Mo kórìíra ìwà ìgbéraga Jakọbu, ati gbogbo àwọn ibi ààbò rẹ̀; n óo mú ọwọ́ kúrò lọ́rọ̀ ìlú náà ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.” +Bí ó bá ku eniyan mẹ́wàá ninu ìdílé kan, gbogbo wọn yóo kú. +Ìparun Israẹli. +OLUWA Ọlọrun fi ìran kan hàn mí! Ó ń kó ọ̀wọ́ eṣú jọ ní àkókò tí koríko ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè, lẹ́yìn tí wọ́n ti gé koríko ti ọba tán. +Nígbà náà ni Amasaya, alufaa Bẹtẹli, ranṣẹ sí Jeroboamu, ọba Israẹli pé: “Amosi ń dìtẹ̀ mọ́ ọ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóo sì ba gbogbo ilẹ̀ yìí jẹ́. +Ó ń wí pé, ‘Jeroboamu yóo kú sójú ogun, gbogbo ilé Israẹli ni a óo sì kó lẹ́rú lọ.’ ” +Amasaya sọ fún Amosi pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ aríran, pada lọ sí ilẹ̀ Juda, máa lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ níbẹ̀, kí wọ́n sì máa fún ọ ní oúnjẹ. +Má sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní Bẹtẹli mọ́, nítorí ibi mímọ́ ni, fún ọba ati fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” +Amosi bá dáhùn, ó ní: “Èmi kì í ṣe wolii tabi ọmọ wolii, darandaran ni mí, èmi a sì tún máa tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́. +OLUWA ló pè mí níbi iṣẹ́ mi, òun ló ní kí n lọ máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún Israẹli, eniyan òun. +Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA nisinsinyii, ṣé o ní kí n má sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli mọ́, kí n má sì waasu fún àwọn ọmọ Isaaki mọ́? +Nítorí náà, gbọ́ ohun tí OLUWA sọ: ‘Iyawo rẹ yóo di aṣẹ́wó láàrin ìlú, àwọn ọmọ rẹ lọkunrin ati lobinrin yóo kú sójú ogun, a óo pín ilẹ̀ rẹ fún àwọn ẹlòmíràn; ìwọ pàápàá yóo sì kú sí ilẹ̀ àwọn alaigbagbọ; láìṣe àní àní, a óo kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ìgbèkùn.’ ” +Nígbà tí àwọn eṣú náà ti jẹ gbogbo koríko ilẹ̀ náà tán, mo ní, “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́ dáríjì àwọn eniyan rẹ. Báwo ni àwọn ọmọ Jakọbu yóo ṣe là, nítorí pé wọ́n kéré níye?” +OLUWA bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, ó ní, “Ohun tí o rí kò ní ṣẹlẹ̀.” +OLUWA Ọlọrun tún fi ìran mìíràn hàn mí: mo rí i tí Ọlọrun pe iná láti fi jẹ àwọn eniyan rẹ̀ níyà. Iná náà jó ibú omi, ráúráú ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó ilẹ̀ pàápàá. +Nígbà náà ni mo dáhùn pé: “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́, dáwọ́ dúró. Báwo ni àwọn ọmọ Jakọbu yóo ṣe là, nítorí wọ́n kéré níye?” +OLUWA bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, ó ní, “Ohun tí o rí kò ní ṣẹlẹ̀.” +OLUWA Ọlọrun tún fi ìran mìíràn hàn mí: mo rí i tí OLUWA mú okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé lọ́wọ́; ó dúró lẹ́bàá ògiri tí a ti fi okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé wọ̀n. +Ó bi mí pé: “Amosi, kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé, “Okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé.” Ó ní: “Wò ó! Mo ti fi okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé sí ààrin àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi; n kò ní fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́. +Gbogbo ibi gíga Isaaki yóo di ahoro, ilé mímọ́ Israẹli yóo parun, n óo yọ idà sí ìdílé ọba Jeroboamu.” +Ìran Nípa Eṣú. +OLUWA Ọlọrun, tún fi ìran mìíràn hàn mí. Lójú ìran, mo rí agbọ̀n èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kan. +N óo yí àsè àjọ̀dún yín pada sí ọ̀fọ̀, n óo sọ orin yín di ẹkún; n óo sán aṣọ ìbànújẹ́ mọ́ gbogbo yín nídìí, n óo sì mú kí orí gbogbo yín pá; ẹ óo dàbí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo, ọjọ́ náà yóo korò ju ewúro lọ.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo rán ìyàn sí ilẹ̀ náà; kì í ṣe ìyàn, oúnjẹ, tabi ti omi, ìran láti ọ̀dọ̀ OLUWA ni kò ní sí. +Wọn yóo máa lọ káàkiri láti òkun dé òkun, láti ìhà àríwá sí ìhà ìlà oòrùn. Wọn yóo máa sá sókè sódò láti wá ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò ní rí i. +Nígbà tó bá yá, àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn wundia yóo dákú nítorí òùngbẹ. +Gbogbo àwọn tí wọn ń fi oriṣa Aṣima ti Samaria búra, tí wọn ń wí pé: ‘Bí oriṣa rẹ ti wà láàyè, ìwọ Dani,’ ati, ‘Bí ọ̀nà Beeriṣeba ti wà láàyè;’ gbogbo wọn yóo ṣubú, wọn kò sì ní dìde mọ́.” +OLUWA bèèrè pé, “Amosi, kí ni ò ń wò yìí?” Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ni.” OLUWA bá sọ pé: “Òpin ti dé sí Israẹli, àwọn eniyan mi, n kò sì ní fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́. +Nígbà tó bá yá, orin inú tẹmpili yóo di ẹkún, òkú yóo sùn lọ kítikìti níbi gbogbo, a óo kó wọn dà síta ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rẹ́ àwọn aláìní jẹ, tí ẹ múra láti pa àwọn talaka run lórí ilẹ̀ patapata. +Ẹ̀ ń sọ pé: “Nígbà wo ni ìsinmi oṣù titun yóo parí, kí á lè rí ààyè ta ọkà wa? Nígbà wo sì ni ọjọ́ ìsinmi yóo kọjá, kí á lè rí ààyè ta alikama, kí á lè gbówó lé ọjà wa, kí á sì lo òṣùnwọ̀n èké, láti rẹ́ àwọn oníbàárà wa jẹ; +kí á lè fi fadaka ra talaka, kí á lè ta aláìní, kí á sì fi owó rẹ̀ ra bàtà, kí á sì ta alikama tí kò dára?” +OLUWA ti fi ògo Jakọbu búra; ó ní, “Dájúdájú n kò ní gbàgbé ẹyọ kan ninu iṣẹ́ ọwọ́ yín. +Ǹjẹ́ kò yẹ kí ilẹ̀ náà mì tìtì nítorí ọ̀rọ̀ yìí kí àwọn eniyan tí ń gbé orí rẹ̀ sì máa ṣọ̀fọ̀? Gbogbo rẹ̀ yóo ru sókè bí odò Naili, yóo máa lọ sókè sódò, yóo sì fà bí odò Naili ti Ijipti. +Ní ọjọ́ náà, n óo mú kí oòrùn wọ̀ ní ọjọ́kanrí, ilẹ̀ yóo sì ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan. +Ìran Nípa Agbọ̀n Èso. +Mo rí OLUWA, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, ó pàṣẹ pé, “Lu àwọn òpó tẹmpili títí tí gbogbo àtẹ́rígbà rẹ̀ yóo fi mì tìtì, tí yóo sì wó lé gbogbo àwọn eniyan lórí. N óo jẹ́ kí ogun pa àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù lára wọn, Kò ní sí ẹyọ ẹnìkan ninu wọn tí yóo lè sálọ, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ẹnìkan tí yóo sá àsálà. +Gbogbo àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi ni ogun yóo pa, gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ pé, ‘Ibi kankan kò ní bá wa!’ +“Ní ọjọ́ náà, n óo gbé àgọ́ Dafidi tí ó ti wó ró. N óo tún odi rẹ̀ mọ, n óo tún un kọ́ yóo sì rí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí. +Àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun àwọn tí wọ́n kù ní Edomu, ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí à ń fi orúkọ mi pè. Èmi OLUWA, tí n óo ṣe bí mo ti wí, èmi ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Ọjọ́ ń bọ̀, tí ọkà yóo so jìnwìnnì,tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè kórè rẹ̀ tánkí àkókò gbígbin ọkà mìíràn tó dé.Ọgbà àjàrà yóo so,tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè fi ṣe waini tánkí àkókò ati gbin òmíràn tó dé.Ọtí waini dídùn yóo máa kán sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá,ọtí waini yóo sì máa ṣàn jáde lára àwọn òkè kéékèèké. +N óo dá ire Israẹli, àwọn eniyan mi, pada,wọn yóo tún àwọn ìlú tí wọ́n ti wó kọ́,wọn yóo sì máa gbé inú wọn.Wọn yóo gbin àjàrà,wọn yóo sì mu ọtí waini rẹ̀.Wọn yóo ṣe ọgbà,wọn yóo sì jẹ èso rẹ̀. +N óo fẹsẹ̀ àwọn eniyan mi múlẹ̀lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,a kò sì ní ṣí wọn nípò pada mọ́lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn.Èmi OLUWA Ọlọrun yín ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Bí wọ́n tilẹ̀ gbẹ́ ilẹ̀ tí ó jìn bí isà òkú, ọwọ́ mi yóo tẹ̀ wọ́n níbẹ̀; bí wọ́n gòkè lọ sí ojú ọ̀run, n óo wọ́ wọn lulẹ̀ láti ibẹ̀. +Bí wọ́n bá sápamọ́ sórí òkè Kamẹli, n óo wá wọn kàn níbẹ̀; n óo sì mú wọn. Bí wọ́n bá sá kúrò níwájú mi, tí wọ́n sápamọ́ sí ìsàlẹ̀ òkun, n óo pàṣẹ fún ejò níbẹ̀, yóo sì bù wọ́n jẹ. +Bí àwọn ọ̀tá bá kó wọn lẹ́rú, tí wọn ń kó wọn lọ, n óo pàṣẹ pé kí àwọn ọ̀tá pa wọ́n. N óo dójúlé wọn láti ṣe wọ́n ní ibi, n kò ní ṣe wọ́n ní rere.” +OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,òun ló fọwọ́ kan ilẹ̀,tí ilẹ̀ sì yọ́,tí gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀,tí gbogbo nǹkan ru sókè bí odò Naili,tí ó sì lọ sílẹ̀ bí odò Naili ti Ijipti; +OLUWA tí ó kọ́ ilé gíga rẹ̀ sí ojú ọ̀run,tí ó gbé awọsanma lé orí ilẹ̀ ayétí ó pe omi òkun jáde,tí ó sì dà á sórí ilẹ̀,OLUWA ni orúkọ rẹ̀. +Ọlọrun ní, “Ṣebí bí ẹ ti jẹ́ sí mi ni àwọn ará Etiopia náà jẹ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Àbí kì í ṣe bí mo ti mú àwọn ará Filistia jáde láti ìlú Kafitori, tí mo mú àwọn Siria jáde láti ìlú Kiri, ni mo mú ẹ̀yin náà jáde láti Ijipti. +Wò ó! Èmi OLUWA Ọlọrun ti fojú sí orílẹ̀-èdè tí ń dẹ́ṣẹ̀ lára, n óo sì pa á run lórí ilẹ̀ ayé; ṣugbọn, n kò ní run gbogbo ìran Jakọbu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“N óo pàṣẹ pé kí wọ́n gbo gbogbo Israẹli jìgìjìgì láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè, bí ìgbà tí wọ́n bá fi ajọ̀ ku èlùbọ́, ṣugbọn kóró kan kò ní bọ́ sílẹ̀. +Ìdájọ́ OLUWA. +Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu, nípa ìfẹ́ Ọlọrun, ati Timoti arakunrin wa, àwa ni à ń kọ ìwé yìí– +A tún ń gbadura pé kí ìgbé-ayé yín lè jẹ́ èyí tí ó wu Oluwa lọ́nà gbogbo, kí iṣẹ́ rere yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ máa tẹ̀síwájú ninu ìmọ̀ Ọlọrun. +Ati pé kí Ọlọrun fun yín ní agbára gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní ìfaradà ninu ohun gbogbo, pẹlu sùúrù ati ayọ̀. Kí ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa tí ó kà yín yẹ láti ní ìpín ninu ogún àwọn eniyan Ọlọrun ninu ìmọ́lẹ̀. +Baba wa náà ni ó gbà wá lọ́wọ́ agbára òkùnkùn, ó sì mú wa wá sinu ìjọba àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀. +Nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ yìí ni a fi ní ìdáǹdè, àní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa. +Eniyan kò lè rí Ọlọrun, ṣugbọn ọmọ yìí ni àwòrán rẹ̀, òun ni àkọ́bí ohun gbogbo tí a dá. +Nítorí pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, lọ́run ati láyé: ati ohun tí a rí, ati ohun tí a kò rí, ìbáà ṣe ìtẹ́ ọba, tabi ìjọba, tabi àwọn alágbára, tabi àwọn aláṣẹ. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá gbogbo nǹkan, nítorí tirẹ̀ ni a sì ṣe dá wọn. +Ó ti wà ṣiwaju ohun gbogbo. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni gbogbo nǹkan sì fi wà létò. +Òun ni orí fún ara, tíí ṣe ìjọ. Òun ni ìbẹ̀rẹ̀, àkọ́bí tí a jí dìde láti inú òkú, kí ó lè wà ní ipò tí ó ga ju gbogbo nǹkan lọ. +Nítorí ó wu Ọlọrun pé kí ohun tí Ọlọrun tìkararẹ̀ jẹ́ máa gbé inú rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. +Sí ìjọ eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Kolose, sí àwọn arakunrin tí ó jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi.Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa kí ó wà pẹlu yín. +Nípa rẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gbogbo nǹkan lọ́kan pẹlu ara rẹ̀, kí alaafia lè dé nípa ikú rẹ̀ lórí agbelebu. Gbogbo nǹkan wá wà ní ìṣọ̀kan, ìbáà ṣe nǹkan ti ayé tabi àwọn nǹkan ti ọ̀run. +Ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ àlejò ati ọ̀tá ninu ọkàn yín nípa iṣẹ́ burúkú yín +ni Ọlọrun wá mú wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara rẹ̀ nípa ikú ọmọ rẹ̀, kí ó lè sọ yín di ẹni tí ó mọ́, tí kò ní àbùkù, tí kò sì ní ẹ̀sùn níwájú rẹ̀, +tí ẹ bá dúró ninu igbagbọ, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ dúró gbọningbọnin, tí ẹ kò kúrò ninu ìrètí ìyìn rere tí ẹ ti gbọ́, tí èmi Paulu jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, tí a ti waasu rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá ayé. +Ní àkókò yìí, mo láyọ̀ ninu ìyà tí mò ń jẹ nítorí yín. Ìyà tí mò ń jẹ ninu ara mi yìí ni èyí tí ó kù tí Kristi ìbá jẹ fún ìjọ, tíí ṣe ara rẹ̀. +Nítorí èyí ni mo ṣe di iranṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Ọlọrun ti fún mi láti ṣe nítorí yín. +Ìjìnlẹ̀ àṣírí nìyí, ó ti wà ní ìpamọ́ láti ìgbà àtijọ́ ati láti ìrandíran, ṣugbọn Ọlọrun fihan àwọn eniyan rẹ̀ ní àkókò yìí. +Àwọn ni ó wu Ọlọrun pé kí wọ́n mọ ọlá ati ògo àṣírí yìí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Àṣírí náà ni pé, Kristi tí ó ń gbé inú yín ni ìrètí ògo. +Kristi yìí ni à ń kéde fun yín, tí à ń kìlọ̀ rẹ̀ fún gbogbo eniyan, tí a fi ń kọ́ gbogbo eniyan ní gbogbo ọgbọ́n, kí á lè sọ gbogbo eniyan di pípé ninu Kristi. +Ohun tí mò ń ṣiṣẹ́ fún nìyí gẹ́gẹ́ bí agbára tí Ọlọrun fún mi, tí ó ń fún mi ní okun. +À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Oluwa wa, Jesu Kristi, nígbà gbogbo tí a bá ń gbadura fun yín. +A ti gbúròó igbagbọ yín ninu Kristi Jesu ati ìfẹ́ tí ẹ ní sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun. +Ìrètí tí ó wà fun yín ni ọ̀run, tí ẹ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìn rere, ni orísun igbagbọ ati ìfẹ́ yín. +Ìyìn rere yìí ti dé ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ó ti dé ọ̀dọ̀ gbogbo aráyé, ó ń so èso, ó sì ń dàgbà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí láàrin ẹ̀yin náà láti ọjọ́ tí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì ti mọ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun nítòótọ́. +Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ti kọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere lọ́dọ̀ Epafirasi, àyànfẹ́, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa. +Òun ni ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín ninu nǹkan ti ẹ̀mí. +Nítorí náà, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ ìròyìn yín, àwa náà kò sinmi láti máa gbadura fun yín. À ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọrun lè jẹ́ kí ẹ mọ ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹlu gbogbo ọgbọ́n, kí ó sì fun yín ní òye nípa nǹkan ti ẹ̀mí. +Ìkíni. +Nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń ṣe akitiyan tó nítorí yín ati nítorí àwọn tí ó wà ní Laodikia ati nítorí àwọn tí kò mọ̀ mí sójú. +Ó sì ti ṣe yín ní pípé ninu rẹ̀. Òun níí ṣe orí fún gbogbo àwọn ẹ̀mí ojú ọ̀run, ìbáà ṣe ìjọba tabi àwọn aláṣẹ. +Ninu Kristi yìí ni a ti kọ yín nílà, kì í ṣe ilà tí a fi ọwọ́ kọ nípa gígé ẹran-ara kúrò, ṣugbọn ilà ti Kristi; +nígbà tí a sin yín ninu omi ìrìbọmi, tí ẹ tún jinde nípa igbagbọ pẹlu agbára Ọlọrun tí ó jí Kristi dìde ninu òkú. +Ẹ̀yin tí ẹ ti di òkú nípa ẹ̀ṣẹ̀ yín, tí ẹ jẹ́ aláìkọlà nípa ti ara, ni Ọlọrun ti sọ di alààyè pẹlu Kristi. Ọlọrun ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. +Ó ti pa àkọsílẹ̀ tí ó lòdì sí wa rẹ́, ó mú un kúrò, ó kàn án mọ́ agbelebu. +Ó gba agbára lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí ojú ọ̀run: ati ìjọba ni, ati àwọn alágbára wọ̀n-ọn-nì; ó bọ́ wọn síhòòhò, ó fi wọ́n ṣẹ̀sín ní gbangba, nígbà tí ó ti ṣẹgun wọn lórí agbelebu. +Nítorí náà ẹ má gbà fún ẹnikẹ́ni kí ó máa darí yín nípa nǹkan jíjẹ tabi nǹkan mímu, tabi nípa ọ̀rọ̀ àjọ̀dún tabi ti oṣù titun tabi ti Ọjọ́ Ìsinmi. +Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àwòjíìjí ohun tí ó ń bọ̀, ṣugbọn nǹkan ti Kristi ni ó ṣe pataki. +Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni da yín lẹ́bi, kí ó sọ fun yín pé kí ẹ máa fi ìyà jẹ ara yín, kí ẹ máa sin àwọn angẹli. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń ṣe ìgbéraga nípa ìran tí ó ti rí, ó ń gbéraga lásán nípa nǹkan ti ara rẹ̀; +kò dì mọ́ ẹni tíí ṣe orí, tí ó mú kí gbogbo ara, ati iṣan, ati ẹran-ara wà pọ̀, tí ó ń mú un dàgbà bí Ọlọrun ti fẹ́. +Ìdí akitiyan mi ni pé kí Ọlọrun lè mu yín ní ọkàn le, kí ó so yín pọ̀ ninu ìfẹ́ ati ọrọ̀ òye tí ó dájú, kí ẹ sì ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àṣírí Ọlọrun, tíí ṣe Kristi fúnrarẹ̀. +Bí ẹ bá ti kú pẹlu Kristi sí àwọn ìlànà ti ẹ̀mí tí a kò rí, kí ló dé tí ẹ fi tún ń pa oríṣìíríṣìí èèwọ̀ mọ́? +“Má fọwọ́ kan èyí,” “Má jẹ tọ̀hún,” “Má ṣegbá, má ṣàwo?” +Gbogbo àwọn nǹkan wọnyi yóo ṣègbé bí ẹ bá ti lò wọ́n tán. Ìlànà ati ẹ̀kọ́ eniyan ni wọ́n. +Ó lè dàbí ẹni pé ọgbọ́n wà ninu àwọn nǹkan wọnyi fún ìsìn ti òde ara ati fún ìjẹra-ẹni-níyà ati fún ìkóra-ẹni-níjàánu. Ṣugbọn wọn kò ṣe anfaani rárá láti jẹ́ kí eniyan borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara. +Ninu Kristi ni Ọlọrun fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n ati ìmọ̀ pamọ́ sí. +Mò ń sọ èyí kí ẹnikẹ́ni má baà fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín jẹ. +Nítorí bí n kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nípa ti ara, sibẹ mo wà pẹlu yín ninu ẹ̀mí. Mo láyọ̀ nígbà tí mo rí ètò tí ó wà láàrin yín ati bí igbagbọ yín ti dúró ninu Kristi. +Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba Kristi Jesu bí Oluwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín ni ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀. +Kí ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ẹ máa dàgbà ninu rẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí igbagbọ yín dúró ṣinṣin bí ẹ ti kọ́ láti ṣe, kí ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo. +Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ayé ati ìtànjẹ lásán sọ yín di ẹrú gẹ́gẹ́ bí àṣà eniyan, ati ìlànà àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí ó yàtọ̀ sí ètò ti Kristi. +Nítorí pé ninu Kristi tí ó jẹ́ eniyan ni ohun tí Ọlọrun fúnrarẹ̀ jẹ́, ń gbé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. +Ìgbé-Ayé Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ninu Kristi. +Nítorí náà, bí a bá ti ji yín dìde pẹlu Kristi, ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run níbi tí Kristi wà, tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. +tí ẹ ti gbé ẹ̀dá titun wọ̀. Èyí ni ẹ̀dá tí ó túbọ̀ ń di titun siwaju ati siwaju gẹ́gẹ́ bí àwòrán ẹni tí ó dá a, tí ó ń mú kí eniyan ní ìmọ̀ Ọlọrun. +Ninu ipò titun yìí, kò sí pé ẹnìkan ni Giriki, ẹnìkan ni Juu; tabi pé ẹnìkan kọlà, ẹnìkan kò kọlà, ẹnìkan aláìgbédè, ẹnìkan ẹlẹ́nu òdì, ẹnìkan ẹrú, ẹnìkan òmìnira. Nítorí Kristi ni ohun gbogbo, tí ó wà ninu ohun gbogbo. +Nítorí náà, ẹ gbé àánú wọ̀ bí ẹ̀wù, ati inú rere, ìrẹ̀lẹ̀, ìwà pẹ̀lẹ́ ati sùúrù, bí ó ti yẹ àwọn ẹni tí Ọlọrun yàn, tí wọ́n sì jẹ́ eniyan Ọlọrun ati àyànfẹ́ rẹ̀. +Ẹ ní ìfaradà láàrin ara yín. Ẹ máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnìkejì rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti dáríjì yín bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí ara yín. +Boríborí gbogbo nǹkan wọnyi, ni pé kí ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀. Ìfẹ́ ni ó so àwọn nǹkan yòókù pọ̀, tí ó sì mú wọn pé. +Kí alaafia láti ọ̀dọ̀ Kristi máa ṣe alákòóso ọkàn yín; nítorí Ọlọrun pè yín láti jẹ́ ara kan nítorí alaafia yìí, ẹ sì máa ṣọpẹ́. +Kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kí ẹ máa fi gbogbo ọgbọ́n kọ́ ara yín, kí ẹ máa fún ara yín ní ìwúrí nípa kíkọ Orin Dafidi, ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá. Ẹ máa kọrin sí Ọlọrun pẹlu ọpẹ́ ninu ọkàn yín. +Ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe, ìbáà jẹ́ pé ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ni tabi pé ẹ̀ ń ṣe nǹkankan ni, ẹ máa ṣe é ní orúkọ Oluwa Jesu. Ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Baba nípasẹ̀ rẹ̀. +Ẹ̀yin aya, ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ kí onigbagbọ máa ṣe. +Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín. Ẹ má ṣe kanra mọ́ wọn. +Ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run, ẹ má lépa àwọn ohun tí ó wà láyé. +Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu ninu ohun gbogbo, nítorí ohun tí ó wu Oluwa nìyí. +Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe rorò mọ́ àwọn ọmọ yín, kí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn má baà bá wọn. +Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn olówó yín lẹ́nu ninu ohun gbogbo. Kí ó má jẹ́ pé nígbà tí wọn bá ń ṣọ́ yín nìkan ni ẹ óo máa ṣiṣẹ́, bí ìgbà tí ó jẹ́ pé eniyan ni ẹ̀ ń fẹ́ tẹ́ lọ́rùn. Ṣugbọn ẹ fi gbogbo ara ṣiṣẹ́, ní ìbẹ̀rù Oluwa. +Ohunkohun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ ṣe é tọkàntọkàn, bí ẹni pé Oluwa ni ẹ̀ ń ṣe é fún, kì í ṣe fún eniyan, +níwọ̀n ìgbà tí ẹ mọ̀ pé ẹ óo rí ogún gbà gẹ́gẹ́ bí èrè láti ọ̀dọ̀ Oluwa. Oluwa Kristi ni ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ ẹrú fún. +Nítorí ẹni tí ó bá ń ṣe àìdára, yóo gba èrè àìdára. Kò ní sí ojuṣaaju. +Nítorí ẹ ti kú, ẹ̀mí yín wà ní ìpamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun. +Nígbà tí Kristi, ẹni tíí ṣe ẹ̀mí yín bá farahàn, ẹ̀yin náà yóo farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ògo. +Nítorí náà, ẹ pa àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀yà ara yín ti ayé run: àwọn bíi àgbèrè, ìwà èérí, ìṣekúṣe, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ati ojúkòkòrò tíí ṣe ìbọ̀rìṣà. +Nítorí nǹkan wọnyi ni ibinu Ọlọrun ṣe ń bọ̀. +Ẹ̀yin náà ti wà lára irú àwọn eniyan wọnyi nígbà kan rí, nígbà tí ẹ̀yin náà ń ṣe nǹkan wọnyi. +Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹ pa gbogbo àwọn nǹkan wọnyi tì: ibinu, inúfùfù, ìwà burúkú, ìsọkúsọ, ọ̀rọ̀ ìtìjú. +Ẹ má purọ́ fún ara yín, nígbà tí ẹ ti bọ́ ara àtijọ́ sílẹ̀ pẹlu iṣẹ́ rẹ̀, +Ìbálò Onigbagbọ pẹlu Ara Wọn. +Ẹ̀yin ọ̀gá, ohun tí ó dára ati ohun tí ó yẹ ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹrú yín. Kí ẹ ranti pé ẹ̀yin náà ní Ọ̀gá kan ní ọ̀run. +Arisitakọsi, ẹlẹ́wọ̀n, ẹlẹgbẹ́ mi ki yín, ati Maku, ìbátan Banaba. Ẹ ti rí ìwé gbà nípa rẹ̀. Tí ó bá dé ọ̀dọ̀ yín, kí ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀. +Jesu tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Jusitu náà ki yín. Àwọn yìí nìkan ni wọ́n kọlà ninu àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ ìjọba Ọlọrun. Ìtùnú ni wọ́n jẹ́ fún mi. +Epafirasi, iranṣẹ Kristi Jesu, ọ̀kan ninu yín, ki yín. Nígbà gbogbo ni ó ń gbadura kíkankíkan fun yín, pé kí ẹ lè dúró ní pípé ati pé kí ẹ lè kún fún gbogbo ohun tíí ṣe ìfẹ́ Ọlọrun. +Nítorí pé mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ti ṣiṣẹ́ pupọ fun yín ati fún àwọn tí ó wà ní Laodikia ati ní Hierapoli. +Luku, àyànfẹ́ oníṣègùn ati Demasi ki yín. +Ẹ kí àwọn arakunrin tí ó wà ní Laodikia. Ẹ kí Nimfa ati ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀. +Nígbà tí ẹ bá ti ka ìwé yìí tán, kí ẹ rí i pé ìjọ tí ó wà ní Laodikia kà á pẹlu. Kí ẹ̀yin náà sì ka ìwé tí a kọ sí àwọn ará Laodikia. +Ẹ sọ fún Akipu pé kí ó má jáfara nípa iṣẹ́ tí ó gbà láti ọ̀dọ̀ Oluwa, kí ó ṣe é parí. +Ìkíni tí èmi Paulu fi ọwọ́ ara mi kọ nìyí. Ẹ ranti pé ninu ẹ̀wọ̀n ni mo wà.Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹlu yín. +Ẹ tẹra mọ́ adura gbígbà. Ẹ máa fi ọkàn bá adura yín lọ. Kí ẹ sì máa dúpẹ́. +Ẹ tún máa gbadura fún wa, pé kí Ọlọrun lè ṣí ìlẹ̀kùn iwaasu fún wa, kí á lè sọ ìjìnlẹ̀ àṣírí Kristi. Nítorí èyí ni mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n. +Kí ẹ gbadura pé kí n lè ṣe àlàyé bí ó ti yẹ. +Ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín pẹlu ọgbọ́n níwájú àwọn alaigbagbọ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àkókò kan kọjá láìjẹ́ pé ẹ lò ó bí ó ti yẹ. +Ọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí ni kí ó máa ti ẹnu yín jáde nígbà gbogbo, ọ̀rọ̀ tí ó bá etí mu, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ láti dá ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ń bá sọ̀rọ̀ lóhùn. +Tukikọsi, àyànfẹ́ ati arakunrin wa, yóo fun yín ní ìròyìn nípa mi. Iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ati ẹrú bí àwa náà ninu iṣẹ́ Oluwa. +Nítorí èyí gan-an ni mo fi rán an wá sọ́dọ̀ yín, kí ẹ lè mọ bí gbogbo nǹkan ti ń lọ fún wa, kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀. +Mo tún rán Onisimu, ọ̀kan ninu yín, tí òun náà jẹ́ àyànfẹ́ ati arakunrin tí ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Gbogbo bí nǹkan bá ti rí níhìn-ín ni wọn óo ròyìn fun yín. +Ọ̀rọ̀ Ìyànjú. +Ní ọdún kẹta ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, Nebukadinesari ọba Babiloni wá gbógun ti Jerusalẹmu, ó sì dótì í. +Ṣugbọn Aṣipenasi sọ fún Daniẹli, pé, ẹ̀rù ń ba òun, kí ọba tí ó ṣètò jíjẹ ati mímu Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má baà lọ ṣe akiyesi pé Daniẹli rù ju àwọn ẹlẹgbẹ́ rè�� lọ, kí òun má baà fi ẹ̀mí òun wéwu lọ́dọ̀ ọba. +Nítorí náà, Daniẹli sọ fún ẹni tí olórí àwọn ìwẹ̀fà yàn láti máa tọ́jú òun ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹtẹẹta pé, +“Dán àwa iranṣẹ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá, máa fún wa ní ẹ̀wà jẹ, kí o sì máa fún wa ní omi lásán mu. +Lẹ́yìn náà, kí o wá fi wá wé àwọn tí wọn ń jẹ lára oúnjẹ àdídùn tí ọba ń jẹ, bí o bá ti wá rí àwa iranṣẹ rẹ sí ni kí o ṣe ṣe sí wa.” +Ó gba ohun tí wọ́n wí, ó sì dán wọn wò fún ọjọ́ mẹ́wàá. +Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwaa, ojú wọn rẹwà, wọ́n sì sanra ju gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ń jẹ oúnjẹ àdídùn tí ọba ń jẹ lọ. +Nítorí náà, ẹni tí ń tọ́jú wọn bẹ̀rẹ̀ sí fún wọn ní ẹ̀wà, dípò oúnjẹ aládùn tí wọn ìbá máa jẹ ati ọtí tí wọn ìbá máa mu. +Ọlọrun fún àwọn ọdọmọkunrin mẹrẹẹrin yìí ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati òye; Daniẹli sì ní ìmọ̀ láti túmọ̀ ìran ati àlá. +Nígbà tí ó tó àkókò tí ọba ti pàṣẹ pé kí wọ́n kó wọn wá, olórí ìwẹ̀fà kó gbogbo wọn wá siwaju rẹ̀. +Ọba pè wọ́n, ó dán wọn wò, ninu gbogbo wọn, kò sì sí ẹni tí ó dàbí Daniẹli, Hananaya, Miṣaeli ati Asaraya. Nítorí náà, wọ́n fi Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba ní ààfin. +OLUWA jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ tẹ Jehoiakimu ọba Juda. Nebukadinesari kó ninu àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun lọ sí ilẹ̀ Ṣinari, ó sì kó wọn sinu ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé oriṣa rẹ̀. +Ninu gbogbo ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ati ìmọ̀ tí ọba bi wọ́n, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn pidánpidán ati àwọn aláfọ̀ṣẹ tí ó wà ní ìjọba rẹ̀ lọ. +Daniẹli sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kinni ìjọba Kirusi. +Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ pé kí ó lọ sí ààrin àwọn ọmọ ọba ati àwọn eniyan pataki pataki ninu àwọn ọmọ Israẹli, +kí ó ṣa àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní àbùkù lára, àwọn tí wọ́n lẹ́wà, tí wọ́n sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n lọ́nà gbogbo, tí wọ́n ní ẹ̀bùn ìmọ̀, ati òye ẹ̀kọ́, tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba, kí á sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ ati èdè àwọn ará Kalidea. +Ọba ṣètò pé kí wọn máa gbé oúnjẹ aládùn pẹlu ọtí waini fún wọn lára oúnjẹ ati ọtí waini ti òun alára. Wọn óo kẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹta, lẹ́yìn náà, wọn óo máa ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ọba. +Daniẹli, ati Hananaya, ati Miṣaeli ati Asaraya wà lára àwọn tí wọ́n ṣà ninu ẹ̀yà Juda. +Olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ titun: Ó sọ Daniẹli ní Beteṣasari, ó sọ Hananaya ní Ṣadiraki, ó sọ Miṣaeli ní Meṣaki, ó sì sọ Asaraya ni Abedinego. +Daniẹli pinnu pé òun kò ní fi oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ, tabi ọtí tí ó ń mu sọ ara òun di aláìmọ́. Nítorí náà, ó lọ bẹ Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ọba, pé kí ó gba òun láàyè kí òun má sọ ara òun di aláìmọ́. +Ọlọrun jẹ́ kí Daniẹli bá ojurere ati àánú olórí àwọn ìwẹ̀fà náà pàdé. +ÌTÀN DANIẸLI ATI ÀWỌN Ọ̀RẸ́ RẸ̀. +Ní ọdún kẹta tí Kirusi jọba ní Pasia, Daniẹli, (tí à ń pè ní Beteṣasari) rí ìran kan. Òtítọ́ ni ìran náà, ó ṣòro láti túmọ̀, ṣugbọn a la ìran náà ati ìtumọ̀ rẹ̀ yé Daniẹli. +Ọwọ́ kan bá dì mí mú, ó gbé mi nílẹ̀, mo da ọwọ́ ati orúnkún mi délẹ̀. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n fún ìbẹ̀rù. +Ẹni náà pè mí, ó ní, “Daniẹli, ẹni tí Ọlọrun fẹ́ràn! Dìde nàró kí o gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ, nítorí ìwọ ni a rán mi sí.” Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo dìde nàró, ṣugbọn mo ṣì tún ń gbọ̀n. +Ó bá dá mi lọ́kàn le, ó ní, “Má bẹ̀rù, Daniẹli, nítorí láti ọjọ́ tí o ti pinnu láti mòye, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ, gbogbo ohun tí ò ń bèèrè ni a ti gbọ́, adura rẹ ni mo sì wá dáhùn. +Angẹli, aláṣẹ ìjọba Pasia dè mí lọ́nà fún ọjọ́ mọkanlelogun; ṣugbọn Mikaeli, ọ̀kan ninu àwọn olórí aláṣẹ, ni ó wá ràn mí lọ́wọ́; nítorí wọ́n dá mi dúró sọ́dọ̀ aláṣẹ ìjọba Pasia. +Kí o lè mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí àwọn eniyan rẹ lẹ́yìn ọ̀la ni mo ṣe wá, nítorí ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú ni ìran tí o rí.” +Nígbà tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo dojúbolẹ̀, mo sì ya odi. +Ẹnìkan tí ó dàbí eniyan wá, ó fi ọwọ́ kàn mí ní ètè; ẹnu mi bá yà, mo sì sọ̀rọ̀. Mo sọ fún ẹni tí ó dúró tì mí pé, “Olúwa mi, gbogbo ara ni ó wó mi, nítorí ìran tí mo rí, ó sì ti rẹ̀ mí patapata. +N kò ní agbára kankan mọ́, kò sì sí èémí kankan ninu mi, báwo ni èmi iranṣẹ rẹ ti ṣe lè bá ìwọ oluwa mi sọ̀rọ̀?” +Ẹni tí ó dàbí eniyan bá tún fi ọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi ní okun. +Ó ní, “Ìwọ tí Ọlọrun fẹ́ràn, má bẹ̀rù, alaafia ni, dá ara yá, kí o sì ṣe ọkàn gírí.”Nígbà tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo tún lágbára sí i; mo bá dáhùn pé, “olúwa mi, máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ lọ, nítorí ìwọ ni ó fún mi lágbára sí i.” +Ní àkókò náà, èmi Daniẹli ń ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹta. +Ó bi mí pé, “Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí mo fi tọ̀ ọ́ wá? Nisinsinyii n óo pada lọ bá aláṣẹ ìjọba Pasia jà, tí mo bá bá a jà tán, aláṣẹ ìjọba Giriki yóo wá. +Kò sí ẹni tí yóo gbèjà mi ninu nǹkan wọnyi àfi Mikaeli, olùṣọ́ Israẹli; Ṣugbọn n óo sọ ohun tí ó wà ninu Ìwé Òtítọ́ fún ọ. +N kò jẹ oúnjẹ aládùn, n kò jẹran, n kò mu ọtí, n kò sì fi òróró para ní odidi ọ̀sẹ̀ mẹtẹẹta náà. +Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kinni ọdún tí à ń wí yìí, mo dúró létí odò Tigirisi. +Bí mo ti gbójú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó wọ aṣọ funfun, ó fi àmùrè wúrà ṣe ìgbànú. +Ara rẹ̀ ń dán bí òkúta olówó iyebíye tí à ń pè ní bẹrili. Ojú rẹ̀ ń kọ mànà bíi mànàmáná, ẹyinjú rẹ̀ sì ń tàn bí iná. Ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí idẹ dídán, ohùn rẹ̀ sì dàbí ohùn ọpọlọpọ eniyan. +Èmi nìkan ni mo rí ìran yìí, àwọn tí wọ́n wà pẹlu mi kò rí i, ṣugbọn ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì sápamọ́. +Èmi nìkan ni mo kù tí mo sì rí ìran ńlá yìí. Kò sí agbára kankan fún mi mọ́; ojú mi sì yipada, ó wá rẹ̀ mí dẹẹ. +Mo bá gbọ́ tí ó sọ̀rọ̀, nígbà tí mo gbọ́ ohùn rẹ̀, mo dojúbolẹ̀, oorun sì gbé mi lọ. +Ìran tí Daniẹli Rí ní Odò Tigirisi. +“Ní ọdún kinni ìjọba Dariusi ará Mede, mo dúró tì í láti mú un lọ́kàn le ati láti bá a fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀. +“Àwọn ọmọ ọba Siria yóo gbá ogun ńlá jọ, wọn yóo sì kó ogun wọn wá, wọn yóo jà títí wọn yóo fi wọ ìlú olódi ti ọ̀tá wọn. +Inú yóo bí ọba Ijipti, yóo sì lọ bá ọba Siria jagun. Ọba Siria yóo kó ọpọlọpọ ogun jọ, ṣugbọn Ijipti yóo ṣẹgun rẹ̀. +Ọba Ijipti óo máa gbéraga nítorí ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí ọpọlọpọ ogun yìí, yóo sì pa ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun, ṣugbọn kò ní borí. +“Nítorí pé ọba Siria yóo tún pada lọ, yóo kó ogun jọ, tí yóo pọ̀ ju ti iṣaaju lọ. Nígbà tí ó bá yá, lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún, yóo pada wá pẹlu ikọ̀ ọmọ ogun tí ó lágbára, pẹlu ọpọlọpọ ihamọra ati ohun ìjà. +Ní àkókò náà, ọ̀pọ̀ eniyan yóo dìde sí ọba Ijipti; àwọn oníjàgídíjàgan láàrin àwọn eniyan rẹ̀ yóo dìde kí ìran yìí lè ṣẹ; ṣugbọn wọn kò ní borí. +Ọba Siria yóo wá dóti ìlú olódi kan, yóo sì gbà á. Àwọn ọmọ ogun Ijipti kò ní lágbára láti dojú ìjà kọ ọ́, àwọn akikanju wọn pàápàá kò ní lágbára mọ́ láti jagun. +Ọba Siria yóo ṣe wọ́n bí ó ti fẹ́ láìsí àtakò, yóo dúró ní Ilẹ̀ Dáradára náà, gbogbo rẹ̀ yóo sì wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. +“Ọba Siria yóo múra láti wá pẹlu gbogbo agbára ìjọba rẹ̀, yóo bá ọba Ijipti dá majẹmu alaafia, yóo sì mú majẹmu náà ṣẹ. Yóo fi ọmọbinrin rẹ̀ fún ọba Ijipti ní aya, kí ó lè ṣẹgun ọba Ijipti. Ṣugbọn yóo kùnà ninu ète rẹ̀. +Lẹ́yìn náà, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè ati àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní etíkun jà, yóo sì ṣẹgun ọpọlọpọ wọn. Ṣugbọn olórí-ogun kan yóo ṣẹgun rẹ̀, yóo sì pa òun náà run. +Yóo pada sí ìlú olódi ti ara rẹ̀, ṣugbọn ijamba yóo ṣe é, yóo sì ṣubú lójú ogun; yóo sì fi bẹ́ẹ̀ parẹ́ patapata. +Nisinsinyii, n óo fi òtítọ́ hàn ọ́.”Angẹli náà tún ní, “Àwọn ọba mẹta ni yóo jẹ sí i ní Pasia; ẹkẹrin yóo ní ọrọ̀ pupọ ju gbogbo àwọn yòókù lọ; nígbà tí ó bá sì ti ipa ọrọ̀ rẹ̀ di alágbára tán, yóo ti gbogbo eniyan nídìí láti bá ìjọba Giriki jagun. +“Ọba mìíràn yóo jẹ lẹ́yìn rẹ̀, yóo sì rán agbowóopá kan kí ó máa gba owó-odè kiri ní gbogbo ìjọba rẹ̀; ní kò pẹ́ kò jìnnà, a óo pa ọba náà, ṣugbọn kò ní jẹ́ ní gbangba tabi lójú ogun.” +Angẹli náà tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé, “Ọba tí yóo tún jẹ ní Siria yóo jẹ́ ọba burúkú. Kì í ṣe òun ni oyè yóo tọ́ sí, ṣugbọn yóo dé lójijì, yóo sì fi àrékérekè gba ìjọba. +Yóo tú àwọn ọmọ ogun ká níwájú rẹ̀, ati ọmọ aládé tí wọn bá dá majẹmu. +Yóo máa fi ẹ̀tàn bá àwọn orílẹ̀-èdè dá majẹmu. Yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbilẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tí ó jọba lé lórí kéré. +Lójijì yóo wá sí àwọn ibi tí ó ní ọrọ̀ jùlọ ní agbègbè náà, yóo máa ṣe ohun tí àwọn baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí. Yóo máa pín ìkógun rẹ̀ fún wọn. Yóo máa wá ọ̀nà ti yóo fi gba àwọn ìlú olódi; ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀ ni. +“Yóo fi gbogbo agbára ati ìgboyà rẹ̀ gbé ogun ńlá ti ọba Ijipti; ọba Ijipti náà yóo gbé ogun ńlá tì í, ṣugbọn kò ní lè dúró níwájú ọba Ijipti nítorí pé wọn yóo dìtẹ̀ mọ́ ọn. +Àwọn tí wọ́n ń bá a jẹ oúnjẹ àdídùn pọ̀ gan-an ni yóo dìtẹ̀ mọ́ ọn; gbogbo ogun rẹ̀ ni yóo túká, ọpọlọpọ yóo sì kú. +Àwọn ọba mejeeji ni yóo pinnu láti hùwà àrékérekè, wọn ó sì máa purọ́ tan ara wọn jẹ níbi tí wọ́n ti jọ ń jẹun; ṣugbọn òfo ni ọgbọ́n àrékérekè wọn yóo já sí; nítorí pé òpin wọn yóo dé ní àkókò tí a ti pinnu. +Ọba Siria yóo wá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹlu gbogbo ìkógun rẹ̀. Ṣugbọn yóo pinnu ní ọkàn rẹ̀ láti gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli. Nígbà tí ó bá ṣe bí ó ti fẹ́ tán, yóo pada sí ilẹ̀ rẹ̀. +“Ní àkókò tí a ti pinnu, yóo tún gbógun ti ilẹ̀ Ijipti, ṣugbọn nǹkan kò ní rí bíi ti àkọ́kọ́ fún un; +“Ọba olókìkí kan yóo wá gorí oyè, pẹlu ipá ni yóo máa fi ṣe ìjọba tirẹ̀, yóo sì máa ṣe bí ó bá ti wù ú. +nítorí pé, àwọn ọmọ ogun Kitimu tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ ojú omi yóo gbógun tì í.“Ẹ̀rù yóo bà á, yóo sì sá pada, yóo fi ibinu ńlá gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli, yóo sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn tí wọ́n ti kọ majẹmu náà sílẹ̀. +Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo wá, wọn yóo sọ Tẹmpili ati ibi ààbò di aláìmọ́, wọn yóo dáwọ́ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo dúró, wọn yóo sì gbé ohun ìríra tíí fa ìsọdahoro kalẹ̀. +Pẹlu ẹ̀tàn, ọba yìí yóo mú àwọn tí wọ́n kọ majẹmu náà sílẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́; ṣugbọn àwọn tí wọ́n mọ Ọlọrun yóo dúró ṣinṣin, wọn óo sì ṣe ẹ̀tọ́. +Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n láàrin wọn óo máa la ọpọlọpọ lọ́yẹ, ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀, wọn óo kú ikú idà, a óo dáná sun wọ́n, a óo kó wọn lẹ́rù, a óo sì kó wọn ní ẹrú lọ. +Nígbà tí a bá ṣẹgun wọn, wọn yóo rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ gbà, ọpọlọpọ yóo sì faramọ́ wọn pẹlu ẹ̀tàn. +Díẹ̀ ninu àwọn ọlọ́gbọ́n yóo kú lójú ogun, a óo fi dán àwọn ọmọ Israẹli wò láti wẹ̀ wọ́n mọ́ ati láti mú gbogbo àbààwọ́n wọn kúrò títí di àkókò ìkẹyìn, ní àkókò tí Ọlọrun ti pinnu. +“Ohun tí ó bá wu ọba náà ni yóo máa ṣe; yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo oriṣa lọ, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo máa sọ̀rọ̀ tó lòdì sí Ọlọrun àwọn ọlọrun, yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i títí ọjọ́ ibinu tí a dá fún un yóo fi pé; nítorí pé ohun tí Ọlọrun ti pinnu yóo ṣẹ. +Kò ní náání oriṣa tí àwọn baba rẹ̀ ń sìn, kò sì ní bìkítà fún èyí tí àwọn obinrin fẹ́ràn; kò ní bìkítà fún oriṣa kankan, nítorí pé yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo wọn lọ. +Dípò gbogbo wọn, yóo máa bọ oriṣa àwọn ìlú olódi; oriṣa tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ rí ni yóo máa sìn, yóo máa fún un ní wúrà ati fadaka, òkúta iyebíye ati àwọn ẹ̀bùn olówó iyebíye. +Pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn tí ń bọ oriṣa àjèjì kan, yóo bá àwọn ìlú olódi tí wọ́n lágbára jùlọ jà. Yóo bu ọlá fún àwọn tí wọ́n bá yẹ́ ẹ sí. Yóo fi wọ́n jẹ olórí ọpọlọpọ eniyan; yóo sì fi ilẹ̀ ṣe ẹ̀bùn fún àwọn tí wọ́n bá fún un lówó. +Lẹ́yìn tí ó bá jọba, ìjọba rẹ̀ yóo pín sí ọ̀nà mẹrin. Àwọn ọba tí yóo jẹ lẹ́yìn rẹ̀ kò ní jẹ́ láti inú ìran rẹ̀, kò sì ní sí èyí tí yóo ní agbára tó o ninu wọn; nítorí a óo gba ìjọba rẹ̀, a óo sì fún àwọn ẹlòmíràn. +“Nígbà tí àkókò ìkẹyìn bá dé, ọba ilẹ̀ Ijipti yóo gbógun tì í; ṣugbọn ọba Siria yóo gbógun tì í bí ìjì líle, pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi. Yóo kọlu àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ lọ bí àgbàrá òjò. +Yóo wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà. Ẹgbẹẹgbẹrun yóo ṣubú, ṣugbọn a óo gba Edomu ati Moabu lọ́wọ́ rẹ̀, ati ibi tí ó ṣe pataki jùlọ ninu ilẹ̀ àwọn ará Amoni. +Yóo gbógun ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, Ijipti pàápàá kò ní lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. +Yóo di aláṣẹ lórí wúrà, fadaka ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ilẹ̀ Ijipti; àwọn ará Libia ati Etiopia yóo máa tẹ̀lé e lẹ́yìn. +Ṣugbọn ìr��yìn kan yóo dé láti ìlà oòrùn ati àríwá tí yóo bà á lẹ́rù, yóo sì fi ibinu jáde lọ kọlu ọpọlọpọ, yóo sì pa wọ́n run. +Yóo kọ́ ààfin ńlá fún ara rẹ̀ ní ààrin òkun ati ní òkè mímọ́ ológo; sibẹ yóo ṣègbé, kò sì ní sí ẹni tí yóo ràn án lọ́wọ́.” +“Ọba Ijipti ní ìhà gúsù yóo lágbára, ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo lágbára jù ú lọ, ìjọba rẹ̀ yóo sì tóbi ju ti ọba lọ. +Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ọba Ijipti yóo ní àjọṣepọ̀ pẹlu ọba Siria, ní ìhà àríwá, ọmọbinrin ọba Ijipti yóo wá sí ọ̀dọ̀ ọba Siria láti bá a dá majẹmu alaafia; ṣugbọn agbára ọmọbinrin náà yóo dínkù, ọba pàápàá ati ọmọ rẹ̀ kò sì ní tọ́jọ́. A óo kọ obinrin náà sílẹ̀, òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀, ati alátìlẹ́yìn rẹ̀. +Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ yóo jọba ní ipò rẹ̀, yóo wá pẹlu ogun, yóo wọ ìlú olódi ọba Siria, yóo bá wọn jagun, yóo sì ṣẹgun wọn. +Yóo kó àwọn oriṣa wọn, ati àwọn ère wọn lọ sí ilẹ̀ Ijipti, pẹlu àwọn ohun èlò olówó iyebíye wọn tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe; kò sì ní bá ọba Siria jagun mọ́ fún ọdún bíi mélòó kan. +Ọba Siria yóo wá gbógun ti ọba Ijipti, ṣugbọn yóo sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀. +Ìjọba Ijipti ati ti Siria. +Angẹli tí ó wọ aṣọ funfun náà ní, “Ní àkókò náà Mikaeli, aláṣẹ ńlá, tí ń dáàbò bo àwọn eniyan rẹ, yóo dìde. Àkókò ìyọnu yóo dé, irú èyí tí kò tíì sí rí láti ọjọ́ tí aláyé ti dáyé; ṣugbọn a óo gba gbogbo àwọn eniyan rẹ, tí a bá kọ orúkọ wọn sinu ìwé náà là. +Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wẹ ara wọn mọ́, tí wọn yóo sọ ara wọn di funfun, wọn yóo sì mọ́; ṣugbọn àwọn ẹni ibi yóo máa ṣe ibi; kò ní sí ẹni ibi tí òye yóo yé; ṣugbọn yóo yé àwọn ọlọ́gbọ́n. +“Láti ìgbà tí wọn yóo mú ẹbọ ojoojumọ kúrò, tí wọn yóo gbé ohun ìríra sí ibi mímọ́, yóo jẹ́ eedegbeje ọjọ́ ó dín ọjọ́ mẹ́wàá (1,290). +Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá forítì í ní gbogbo eedegbeje ọjọ́ ó lé ọjọ́ marundinlogoji (1,335) náà. +“Ṣugbọn, ìwọ Daniẹli, máa ṣe tìrẹ lọ títí dé òpin. O óo lọ sí ibi ìsinmi, ṣugbọn lọ́jọ́ ìkẹyìn, o óo dìde nílẹ̀ o óo sì gba ìpín tìrẹ tí a ti fi sílẹ̀ fún ọ.” +Ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó ti kú, tí wọ́n ti sin ni yóo jí dìde, àwọn kan óo jí sí ìyè ainipẹkun, àwọn mìíràn óo sì jí sí ìtìjú ati ẹ̀sín ainipẹkun. +Àwọn ọlọ́gbọ́n yóo máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run, àwọn tí wọn ń yí eniyan pada sí ọ̀nà òdodo yóo máa tàn bí ìràwọ̀ lae ati títí lae.” +Ó ní, “Ṣugbọn ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé, kí o sì fi èdìdì dì í títí di àkókò ìkẹyìn. Nítorí àwọn eniyan yóo máa sá síhìn-ín, sá sọ́hùn-ún, ìmọ̀ yóo sì pọ̀ sí i.” +Nígbà náà ni mo rí i tí àwọn meji dúró létí bèbè odò kan, ọ̀kan lápá ìhín, ọ̀kan lápá ọ̀hún. +Ọ̀kan ninu wọn bi ẹni tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò pé, “Nígbà wo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani lẹ́rù wọnyi yóo dópin?” +Ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò na ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè ọ̀run, mo sì gbọ́ tí ó fi orúkọ ẹni tí ó wà láàyè títí lae búra pé, “Ọdún mẹta ààbọ̀ ni yóo jẹ́. Nígbà tí wọn bá gba agbára lọ́wọ́ àwọn eniyan Ọlọrun patapata, ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀.” +Mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ń sọ kò yé mi. Mo bá bèèrè pé, “Olúwa mi, níbo ni nǹkan wọnyi yóo yọrí sí?” +Ó dáhùn pé, “Ìwọ Daniẹli, máa bá tìrẹ lọ, nítorí a ti pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́, a sì ti fi èdìdì dì í, títí di àkókò ìkẹyìn. +Àkókò Ìkẹyìn. +Ní ọdún keji tí Nebukadinesari gun orí oyè, ó lá àwọn àlá kan; àlá náà bà á lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi lè sùn mọ́ lóru ọjọ́ náà. +Wọ́n dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ẹni náà láyé yìí, tí ó lè sọ ohun tí kabiyesi fẹ́ kí á sọ, kò sí ọba ńlá tabi alágbára kankan tí ó tíì bèèrè irú nǹkan yìí lọ́wọ́ pidánpidán kan, tabi lọ́wọ́ àwọn aláfọ̀ṣẹ, tabi lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea rí. +Ohun tí ọba ń bèèrè yìí le pupọ, kò sí ẹni tí ó lè ṣe é, àfi àwọn oriṣa, nítorí pé àwọn kì í ṣe ẹlẹ́ran ara.” +Nítorí náà inú ọba ru, ó sì bínú gidigidi, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run. +Àṣẹ jáde lọ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n; wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti pa wọ́n. +Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, tí ọba pàṣẹ fún pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni; ó fi ọgbọ́n ati ìrẹ̀lẹ̀ bá a sọ̀rọ̀, +ó ní, “Kí ló dé tí àṣẹ ọba fi le tó báyìí?” Arioku bá sọ bí ọ̀rọ̀ ti rí fún un. +Lẹsẹkẹsẹ, Daniẹli lọ bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ọba pé kí ó dá àkókò fún òun, kí òun lè wá rọ́ àlá náà fún ọba, kí òun sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀. +Daniẹli bá lọ sí ilé, ó sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀: Hananaya, Miṣaeli, ati Asaraya, +pé kí wọ́n gbadura sí Ọlọrun ọ̀run fún àánú láti mọ àlá ọba ati ìtumọ̀ rẹ̀, kí wọ́n má baà pa òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ òun run pẹlu àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni. +Ọlọrun bá fi àṣírí náà han Daniẹli ní ojúran, lóru. Ó sì yin Ọlọrun ọ̀run lógo. +Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n pe àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn oṣó ati àwọn ará Kalidea jọ, kí wọ́n wá rọ́ àlá òun fún òun. Gbogbo wọn sì wá siwaju ọba. +Ó ní, “Ẹni ìyìn ni Ọlọrun títí ayérayé,ẹni tí ó ní ọgbọ́n ati agbára. +Òun ní ń yí ìgbà ati àkókò pada;òun níí mú ọba kan kúrò lórí ìtẹ́,tíí sì í fi òmíràn jẹ.Òun níí fi ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́ntíí sì í fi ìmọ̀ fún àwọn ọ̀mọ̀ràn. +Òun níí fi àṣírí ati ohun ìjìnlẹ̀ hàn;ó mọ ohun tí ó wà ninu òkùnkùn,ìmọ́lẹ̀ sì ń bá a gbé. +Ìwọ Ọlọrun àwọn baba mi,ni mo fi ọpẹ́ ati ìyìn fún,nítorí o fún mi ní ọgbọ́n ati agbára,o sì ti fi ohun tí a bèèrè hàn mí,nítorí o ti fi ohun tí ọba ń bèèrè hàn wá.” +Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, ẹni tí ọba yàn pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, ó sọ fún un pé, “Má pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, n óo sì túmọ̀ àlá rẹ̀ fún un.” +Arioku bá mú Daniẹli lọ sí ọ̀dọ̀ ọba kíákíá. Ó sọ fún ọba pé: “Kabiyesi, mo ti rí ọkunrin kan ninu àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú wá láti Juda, tí ó le túmọ̀ àlá náà fún ọba.” +Ọba bi Daniẹli, tí wọ́n sọ ní Beteṣasari ní èdè Babiloni pé, “Ǹjẹ́ o lè rọ́ àlá mi fún mi, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀?” +Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ọlọ́gbọ́n kan, tabi aláfọ̀ṣẹ, tabi pidánpidán, tabi awòràwọ̀ tí ó lè sọ àṣírí ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ọba ń bèèrè yìí fún un. +Ṣugbọn Ọlọrun kan ń bẹ ní ọ̀run, tí ń fi àṣírí nǹkan ìjìnlẹ̀ hàn. Òun ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han Nebukadinesari ọba. Àlá tí o lá, ati ìran tí o rí ní orí ibùsùn rẹ nìyí: +“Kabiyesi! Bí o ti sùn, ò ń ronú ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la, ẹni tí ń fi ohun ìjìnlẹ̀ han ni sì fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ hàn ọ́. +Ọba sọ fún wọn pé, “Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù pupọ, mo sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ rẹ̀.” +Ní tèmi, kì í ṣe pé mo gbọ́n ju àwọn yòókù lọ ni a ṣe fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí hàn mí, bíkòṣe pé kí ọba lè mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kí òye ohun tí ó ń rò sì lè yé e. +“Kabiyesi, o rí ère kan níwájú rẹ ní ojúran, ère yìí tóbi gan-an, ó mọ́lẹ̀, ó ń dán, ìrísí rẹ̀ sì bani lẹ́rù. +Wúrà ni orí rẹ̀, àyà ati apá rẹ̀ jẹ́ fadaka, ikùn rẹ̀ títí dé itan sì jẹ́ idẹ. +Irin ni òkè ẹsẹ̀ rẹ̀, ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ irin tí a lú pọ̀ mọ́ amọ̀. +Bí o ti ń wò ó, òkúta kan là, ó sì ré bọ́ láti òkè, ó bá ère náà ní ẹsẹ̀ mejeeji tí ó jẹ́ àdàlú irin ati amọ̀, mejeeji sì fọ́ túútúú. +Lẹ́sẹ̀kan náà òkúta yìí bá fọ́ gbogbo ère náà, ati irin, ati amọ̀, ati idẹ, ati fadaka ati wúrà, ó rún gbogbo wọn wómúwómú, títí wọ́n fi dàbí ìyàngbò ní ibi ìpakà. Lẹ́yìn náà, afẹ́fẹ́ fẹ́ wọn lọ, a kò sì rí wọn mọ́ rárá. Òkúta tí ó kọlu ère náà di òkè ńlá, ó sì bo gbogbo ayé. +“Àlá náà nìyí; nisinsinyii, n óo sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. +Kabiyesi, ìwọ ọba àwọn ọba ni Ọlọrun ọ̀run fún ní ìjọba, agbára, ipá ati ògo. +Ọlọrun fi gbogbo eniyan jìn ọ́, níbi yòówù tí wọn ń gbé, ati gbogbo ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, pé kí o máa jọba lórí wọn, ìwọ ni orí wúrà náà. +Lẹ́yìn rẹ ni ìjọba mìíràn yóo dìde tí kò ní lágbára tó tìrẹ. Lẹ́yìn èyí ni ìjọba kẹta, tí ó jẹ́ ti idẹ, yóo jọba lórí gbogbo ayé. +Àwọn ará Kalidea bá dá ọba lóhùn pé, “Kí ọba pẹ́! Rọ́ àlá rẹ fún àwa iranṣẹ rẹ, a óo sì túmọ̀ rẹ̀.” +Nígbà tí ó bá yá, ìjọba kẹrin yóo dé, tí yóo le koko bíi irin (nítorí pé irin a máa fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́ ni); bíi irin ni ìjọba yìí yóo fọ́ àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ túútúú. +Bí o sì ti rí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ ati ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó jẹ́ àdàlú irin ati amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóo pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ṣugbọn agbára irin yóo hàn lára rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀. +Bí ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ sì ti jẹ́ àdàlú amọ̀ ati irin, bẹ́ẹ̀ ni apá kan ìjọba náà yóo lágbára, apá kan kò sì ní lágbára. +Bí o ti rí amọ̀ tí ó dàpọ̀ mọ́ irin, bẹ́ẹ̀ ni àwọn apá kinni keji yóo máa dàpọ̀ ní igbeyawo, ṣugbọn wọn kò ní darapọ̀, gẹ́gẹ́ bí irin kò ti lè darapọ̀ mọ́ amọ̀. +Ní àkókò àwọn ìjọba wọnyi ni Ọlọrun ọ̀run yóo gbé ìjọba kan dìde tí a kò ní lè parun, a kò sì ní fi ìjọba náà fún ẹlòmíràn. Yóo fọ́ àwọn ìjọba wọnyi túútúú, yóo pa wọ́n run, yóo sì dúró laelae. +Bí o ti rí i pé ara òkè kan ni òkúta yìí ti là, láìjẹ́ pé eniyan kan ni ó là á, tí o sì rí i pé ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wúrà túútúú, Ọlọrun tí ó tóbi ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han ọba. Òtítọ́ ni àlá yìí, ìtumọ̀ rẹ̀ sì dájú.” +Ọba bá wólẹ̀ níwájú Daniẹli, ó fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n rúbọ kí wọ́n sì sun turari sí Daniẹli. +Ọba sọ fún Daniẹli pé, “Láìsí àní àní, Ọlọrun rẹ ni Ọlọrun àwọn ọlọrun, ati OLUWA àwọn ọba, òun níí fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ han eniyan, nítorí pé àṣírí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí gan-an ni o sọ.” +Ọba dá Daniẹli lọ́lá, ó kó oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn ńláńlá fún un, ó sì fi ṣe olórí gbogbo agbègbè Babiloni, ati olórí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní Babiloni. +Daniẹli gba àṣẹ lọ́wọ́ ọba, ó fi Ṣadiraki, Meṣaki, ati Abedinego ṣe alákòóso àwọn agbègbè Babiloni, ṣugbọn òun wà ní ààfin. +Ṣugbọn ọba dá wọn lóhùn, pé, “Ohun tí mo bá sọ abẹ ni ó gé e; bí ẹ kò bá lè rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fà yín ya ní tapá-titan, ilé yín yóo sì di àlàpà. +Ṣugbọn bí ẹ bá rọ́ àlá náà, tí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹ óo gba ẹ̀bùn, ìdálọ́lá ati ẹ̀yẹ ńlá, nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.” +Wọ́n dá ọba lóhùn lẹẹkeji pé, “Kí kabiyesi rọ́ àlá rẹ̀ fún wa, a óo sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.” +Ọba dá wọn lóhùn pé, “Mo mọ̀ dájú pé ẹ kàn fẹ́ máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò ni, nítorí ẹ ti mọ̀ pé bí mo ti wí ni n óo ṣe. +Bí ẹ kò bá rọ́ àlá mi fún mi, ìyà kanṣoṣo ni n óo fi jẹ yín. Gbogbo yín ti gbìmọ̀ pọ̀ láti máa parọ́, ati láti máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò. Ẹ rọ́ àlá mi fún mi, n óo sì mọ̀ dájú pé ẹ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.” +Àlá Nebukadinesari. +Nebukadinesari fi kìkì wúrà yá ère kan tí ó ga ní ọgọta igbọnwọ (mita 27), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹfa (mita 2.7). Ó gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura ní agbègbè Babiloni. +Ìwọ ọba ni o pàṣẹ pé nígbàkúùgbà tí ẹnikẹ́ni bá ti gbọ́ ìró fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, kí ó wólẹ̀, kí ó tẹríba fún ère tí o gbé kalẹ̀, +ati pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sọ ọ́ sinu adágún iná tí ń jó. +Àwọn Juu mẹta kan tí ń jẹ́ Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, tí o fi ṣe alákòóso àwọn agbègbè ní ìjọba Babiloni tàpá sí àṣẹ ọba, wọn kò sin ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.” +Inú bí ọba gidigidi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn mẹtẹẹta wá siwaju òun, wọ́n bá kó Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego lọ siwaju ọba. +Ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé nítòótọ́ ni ẹ kò fi orí balẹ̀, kí ẹ sì sin ère wúrà tí mo gbé kalẹ̀? +Nisinsinyii, bí ẹ bá ti gbọ́ ìró ipè, fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, tí ẹ bá wólẹ̀, tí ẹ sì sin ère tí mo ti yá, ó dára, ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò wólẹ̀, wọn óo gbe yín sọ sinu adágún iná ìléru. Kò sì sí ọlọrun náà tí ó lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?” +Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, kò yẹ kí á máa bá ọ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí. +Bí o bá sọ wá sinu iná, Ọlọrun wa tí à ń sìn lè yọ wá ninu adágún iná, ó sì lè gbà wá lọ́wọ́ ìwọ ọba pàápàá. +Ṣugbọn bí kò bá tilẹ̀ gbà wá, a fẹ́ kí ọba mọ̀ pé a kò ní fi orí balẹ̀, kí á sin ère wúrà tí ó gbé kalẹ̀.” +Inú bá bí Nebukadinesari gidigidi, ojú rẹ̀ yipada sí Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n dá iná, kí ó gbóná ní ìlọ́po meje ju bíí tií máa ń gbóná tẹ́lẹ̀ lọ. +Ó pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn olórí ati àwọn gomina, àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn akápò, àwọn onídàájọ́ ati àwọn alákòóso ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè Babiloni wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí òun gbé kalẹ̀. +Ó tún pàṣẹ pé kí àwọn akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, kí wọ́n sì sọ wọ́n sinu adágún iná. +Wọ́n di àwọn mẹtẹẹta pẹlu agbádá, ati aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati fìlà wọn, ati àwọn aṣọ wọn mìíràn, wọ́n sì sọ wọ́n sí ààrin adágún iná tí ń jó. +Nítorí bí àṣẹ ọba ti le tó, ati bí adágún iná náà ti gbóná tó, ahọ́n iná tí ń jó bùlàbùlà jó àwọn tí wọ́n gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sinu rẹ̀ ní àjópa. +Nítorí dídì tí wọ́n di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, wọ́n ṣubú lulẹ̀ sí ààrin iná náà. +Lójijì Nebukadinesari ta gìrì, ó sáré dìde, ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Ṣebí eniyan mẹta ni a dì, tí a gbé sọ sinu iná?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kabiyesi.” +Ó ní, “Ẹ wò ó, eniyan mẹrin ni mo rí yìí, wọ́n wà ní títú sílẹ̀, wọ́n ń rìn káàkiri láàrin iná, iná kò sì jó wọn, Ìrísí ẹni kẹrin dàbí ti ẹ̀dá ọ̀run.” +Nebukadinesari ọba bá lọ sí ẹnu ọ̀nà adágún iná náà, ó kígbe pé, “Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, ẹ̀yin iranṣẹ Ọlọrun alààyè, ẹ jáde wá!” Wọ́n bá jáde kúrò ninu iná lẹsẹkẹsẹ. +Gbogbo àwọn baálẹ̀ ìgbèríko, àwọn olórí, àwọn gomina, ati àwọn ìgbìmọ̀ ọba, kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí i pé iná kò jó àwọn ọkunrin wọnyi, irun orí wọn kò rùn, ẹ̀wù wọn kò yipada, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tilẹ̀ gbóòórùn iná lára wọn. +Nebukadinesari bá dáhùn pé “Ògo ni fún Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e, tí wọn kò ka àṣẹ ọba sí, tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu, dípò kí wọ́n sin ọlọrun mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọrun wọn. +“Nítorí náà, mo pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, tabi orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati ti Abedinego, fífà ni a ó fa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ya ní tapá-titan, a ó sì sọ ilé rẹ̀ di ahoro; nítorí kò sí ọlọrun mìíràn tí ó lè gbani là bẹ́ẹ̀.” +Nítorí náà, gbogbo wọn wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère náà, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀. +Ọba bá gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sí ipò gíga ní ìgbèríko Babiloni. +Akéde bá kígbe sókè, ó kéde pé, “Ọba ní kí á pàṣẹ fun yín, gbogbo eniyan, ẹ̀yin orílẹ̀, ati oniruuru èdè +pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìró fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, kí ẹ dojúbolẹ̀ kí ẹ sin ère wúrà tí ọba Nebukadinesari gbé kalẹ̀. +Ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó sin ère náà, lẹsẹkẹsẹ ni a óo gbé e sọ sinu adágún iná.” +Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró àwọn ohun èlò orin náà, gbogbo wọn wólẹ̀, wọ́n sì sin ère wúrà tí Nebukadinesari, ọba gbé kalẹ̀. +Àwọn ará Kalidea kan wá siwaju ọba, wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn Juu pẹlu ìríra, wọ́n ní, +“Kí ọba kí ó pẹ́! +Nebukadinesari Pàṣẹ pé kí Gbogbo Eniyan máa Sin Ère Wúrà tí ó gbé kalẹ̀. +Ọba Babiloni ranṣẹ sí gbogbo àwọn eniyan, ati gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ní gbogbo ayé, pé:“Kí alaafia wà pẹlu yín! +“Nígbà tí mo sùn, mo rí igi kan láàrin ayé, lójú ìran, igi náà ga lọpọlọpọ. +Igi náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi, ó sì lágbára; orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run, kò sí ibi tí wọn kò ti lè rí i ní gbogbo ayé. +Ewé rẹ̀ lẹ́wà, ó so jìnwìnnì, oúnjẹ wà lórí rẹ̀ fún gbogbo eniyan, abẹ́ rẹ̀ ni àwọn ẹranko ń gbé, orí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ni àwọn ẹyẹ ń sùn. Èso rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀dá alààyè ń jẹ. +“Ní ojúran, lórí ibùsùn mi, mo rí olùṣọ́ kan, Ẹni Mímọ́, +ó kígbe sókè pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀, gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, gbọn gbogbo ewé ati èso rẹ̀ dànù; kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, kí àwọn ẹyẹ sì fò kúrò lórí ẹ̀ka rẹ̀. +Ṣugbọn fi kùkùté, ati gbòǹgbò rẹ̀ sílẹ̀ ninu ìdè irin ati ti idẹ ninu pápá.“ ‘Jẹ́ kí ìrì sẹ̀ sí i lára, kí ó máa bá àwọn ẹranko jẹ koríko; +kí ọkàn rẹ̀ sì yipada kúrò ní ọkàn eniyan sí ti ẹranko fún ọdún meje. +Láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ ni ìdájọ́ yìí ti wá, ìpinnu náà jẹ́ ti àwọn Ẹni Mímọ́; kí gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù ú níí máa gbé ìjọba lé lọ́wọ́, pàápàá láàrin àw���n ẹni tí ó rẹlẹ̀ jùlọ.’ +“Ìran tí èmi Nebukadinesari rí nìyí. Ìwọ Beteṣasari, sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ìjọba mi kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣugbọn o lè ṣe é, nítorí pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ.” +Ọkàn Daniẹli, tí wọn ń pè ní Beteṣasari, pòrúúruù fún ìgbà díẹ̀, ẹ̀rù sì bà á. Ọba bá sọ fún un pé: “Má jẹ́ kí àlá yìí ati ìtumọ̀ rẹ̀ bà ọ́ lẹ́rù.”Beteṣasari dáhùn pé, “olúwa mi, kí àlá yìí ṣẹ mọ́ àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ lára, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì dà lé àwọn ọ̀tá rẹ lórí. +Ó tọ́ lójú mi láti fi àmì ati iṣẹ́ ìyanu, tí Ọlọrun tí ó ga jùlọ ṣe fún mi, hàn. +Igi tí o rí, tí ó dàgbà, tí ó lágbára, tí orí rẹ̀ sì kan ọ̀run dé ibi pé gbogbo eniyan lè rí i, +tí ewé rẹ̀ lẹ́wà, tí ó so jìnwìnnì, tí èso rẹ̀ jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá, tí gbogbo àwọn ẹranko ń gbé abẹ́ rẹ̀, tí àwọn ẹyẹ sì ń sùn lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀. +“Ìwọ ọba ni igi yìí, ìwọ ni o dàgbà, tí o di igi ńlá, tí o sì lágbára. Òkìkí rẹ kàn dé ọ̀run, ìjọba rẹ sì kárí gbogbo ayé. +Olùṣọ́, Ẹni Mímọ́ tí ọba rí tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, tí ó ń wí pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀ kí o sì pa á run, ṣugbọn kí ó ku kùkùté ati gbòǹgbò rẹ̀ ninu ilẹ̀, kí ó wà ninu ìdè irin ati ti idẹ, ninu pápá oko tútù, kí ìrì sẹ̀ sí i lára, kí ó máa bá àwọn ẹranko jẹ káàkiri fún ọdún meje.’ +“Kabiyesi, ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: Àṣẹ tí Ẹni Gíga Jùlọ pa nípa oluwa mi, ọba ni. +A óo lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo sì máa bá àwọn ẹranko inú igbó gbé; o óo máa jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì yóo sì sẹ̀ sí ọ lára fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹni tí ó bá wù ú níí sì í gbé e lé lọ́wọ́. +Olùṣọ́ náà pàṣẹ pé kí á fi gbòǹgbò igi náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀; ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, dájúdájú, o óo tún pada wá jọba, nígbà tí o bá gbà pé Ọlọrun ni ọba gbogbo ayé. +Nítorí náà, kabiyesi, gba ìmọ̀ràn tí n óo fún ọ yìí; jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀, sì máa ṣe òdodo, jáwọ́ ninu ìwà ìkà, máa ṣàánú fún àwọn tí a ni lára, bóyá èyí lè mú kí àkókò alaafia rẹ gùn sí i.” +Gbogbo nǹkan wọnyi sì ṣẹ mọ́ Nebukadinesari ọba lára. +Ní ìparí oṣù kejila, bí ó ti ń rìn lórí òrùlé ààfin Babiloni, +“Iṣẹ́ rẹ̀ tóbi gan-an!Iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sì lágbára lọpọlọpọ!Títí ayérayé ni ìjọba rẹ̀,àtìrandíran rẹ̀ ni yóo sì máa jọba. +ó ní, “Ẹ wo bí Babiloni ti tóbi tó, ìlú tí mo fi ipá ati agbára mi kọ́, tí mo sọ di olú-ìlú fún ògo ati ọlá ńlá mi.” +Kí ó tó wí bẹ́ẹ̀ tán, ẹnìkan fọhùn láti ọ̀run, ó ní, “Nebukadinesari ọba, gbọ́ ohun tí a ti pinnu nípa rẹ: a ti gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ rẹ, +a óo lé ọ kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo máa bá àwọn ẹranko gbé, o óo sì máa jẹ koríko bíi mààlúù fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé, Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ati pé ẹni tí ó bá wù ú ní í máa gbé e lé lọ́wọ́.” +Lẹsẹkẹsẹ ni ọ̀rọ̀ náà ṣẹ mọ́ Nebukadinesari lára. Wọ́n lé e kúrò láàrin àwọn eniyan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko bíi mààlúù. Ìrì sẹ̀ sí i lára títí tí irun orí rẹ̀ fi gùn bí ìyẹ́ idì, èékánná rẹ̀ sì dàbí ti ẹyẹ. +Nebukadinesari ní, “Lẹ́yìn ọdún meje náà, èmi, Nebukadinesari, gbé ojú sí òkè ọ̀run, iyè mi pada bọ̀ sípò. Mo yin Ẹni Gíga Jùlọ, mo fi ọlá ati ògo fún Ẹni Ayérayé. “Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ̀láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀,àní, láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀. +Gbogbo aráyé kò jámọ́ nǹkankan lójú rẹ̀;a sì máa ṣe bí ó ti wù ú láàrin àwọn aráyéati láàrin àwọn ogun ọ̀run.Kò sí ẹni tí ó lè ká a lọ́wọ́ kò,tabi tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. +“Ní àkókò gan-an tí iyè mi pada bọ̀ sípò, ògo, ọlá, ati iyì ìjọba mi náà sì tún pada sọ́dọ̀ mi. Àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn ìjòyè mi wá mi kàn, wọ́n gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀, ìjọba mi tún fi ìdí múlẹ̀, mo sì níyì ju ti àtẹ̀yìnwá lọ ní gbogbo ọ̀nà. +“Ẹ gbọ́, èmi Nebukadinesari, fi ìyìn, ògo, ati ọlá fún ọba ọ̀run. Nítorí pé gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ pé, ọ̀nà rẹ̀ tọ́, ó sì lè rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀.” +“Èmi, Nebukadinesari wà ninu ìdẹ̀ra ní ààfin mi, nǹkan sì ń dára fún mi. +Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù. Èrò ọkàn mi ati ìran tí mo rí lórí ibùsùn mi kó ìdààmú bá mi. +Nítorí náà, mo pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Babiloni wá sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n wá túmọ̀ àlá náà fún mi. +Gbogbo àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea, ati àwọn awòràwọ̀ bá péjọ siwaju mi; mo rọ́ àlá náà fún wọn, ṣugbọn wọn kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. +Lẹ́yìn gbogbo wọn patapata ni Daniẹli dé, tí a sọ ní Beteṣasari, orúkọ oriṣa mi, Daniẹli yìí ní ẹ̀mí Ọlọrun ninu. Mo rọ́ àlá mi fún un, mo ní: +Beteṣasari, olórí gbogbo àwọn pidánpidán, mo mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ, ati pé o mọ gbogbo àṣírí. Gbọ́ àlá mi kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi. +Àlá Keji tí Nebukadinesari Lá. +Ní ọjọ́ kan, Beṣasari ọba, se àsè ńlá kan fún ẹgbẹrun (1,000) ninu àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì ń mu ọtí níwájú wọn. +Nígbà tí ayaba gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ó wọ inú gbọ̀ngàn àsè náà, ó sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, kí ọba kí ó pẹ́, má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí dààmú rẹ tabi kí ó mú kí ojú rẹ fàro. +Ẹnìkan ń bẹ ní ìjọba rẹ tí ó ní ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ninu. Ní àkókò baba rẹ, a rí ìmọ́lẹ̀, ìmọ̀, ati ọgbọ́n bíi ti Ọlọrun ninu rẹ̀. Òun ni baba rẹ, Nebukadinesari ọba, fi ṣe olórí gbogbo àwọn pidánpidán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn Kalidea ati àwọn awòràwọ̀; +nítorí pé Daniẹli, tí ọba sọ ní Beteṣasari, ní ìmọ̀ ati òye láti túmọ̀ àlá, ati láti ṣe àlàyé ohun ìjìnlẹ̀, ati láti yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú. Ranṣẹ pe Daniẹli yìí, yóo sì sọ ìtumọ̀ fún ọ.” +Wọ́n bá mú Daniẹli wá siwaju ọba. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ẹrú, tí baba mi kó wá láti ilẹ̀ Juda? +Mo ti gbọ́ pé ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ń bẹ ninu rẹ; ati pé o ní ìmọ̀, òye, ati ọgbọ́n tí kò lẹ́gbẹ́. +Gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ati aláfọ̀ṣẹ wá siwaju mi, wọ́n gbìyànjú láti ka àkọsílẹ̀ yìí, kí wọ́n sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè ṣe é. +Mo ti gbọ́ nípa rẹ pé o lè túmọ̀ ohun ìjìnlẹ̀, o sì lè yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú; nisinsinyii, bí o bá lè ka àkọsílẹ̀ yìí, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, wọn óo wọ̀ ọ́ ní aṣọ elése àlùkò, wọn óo sì fi ẹ̀gbà wúrà sí ọ lọ́rùn, o óo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ní ìjọba mi.” +Daniẹli dá ọba lóhùn, ó ní, “Jẹ́ kí ẹ̀bùn rẹ máa gbé ọwọ́ rẹ, kí o sì fi ọrẹ rẹ fún ẹlòmíràn. Ṣugbọn n óo ka àkọsílẹ̀ náà fún ọba, n óo sì túmọ̀ rẹ̀. +“Kabiyesi, Ọlọrun tí ó ga jùlọ fún Nebukadinesari, baba rẹ ní ìjọba, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó fún un ní ògo ati ọlá. +Nítorí pé Ọlọrun sọ ọ́ di ẹni ńlá, gbogbo eniyan, gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà ń tẹríba fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. A máa pa ẹni tí ó bá fẹ́, a sì máa dá ẹni tí ó fẹ́ sí. A máa gbé ẹni tí ó bá fẹ́ ga, a sì máa rẹ ẹni tí ó bá wù ú sílẹ̀. +Nígbà tí ó tọ́ ọtí náà wò, ó pàṣẹ pé kí wọn kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí Nebukadinesari, baba rẹ̀, kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, kí òun, ati àwọn ìjòyè òun, àwọn ayaba ati àwọn obinrin òun lè máa fi wọ́n mu ọtí. +Ṣugbọn nígbà tí ó gbé ara rẹ̀ ga, tí ó sì ṣe oríkunkun, a mú un kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, a sì mú ògo rẹ̀ kúrò. +A lé e kúrò láàrin àwọn ọmọ eniyan, ọkàn rẹ̀ dàbí ti ẹranko. Ó ń bá àwọn ẹranko gbé inú igbó. Ó ń jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì sì sẹ̀ sí i lára, títí ó fi mọ̀ pé Ọlọrun tí ó ga jùlọ, ni ó ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, tí ó sì ń gbé e fún ẹni tí ó bá wù ú. +“Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ ọmọ rẹ̀ Beṣasari, o kọ̀, o kò rẹ ara rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. +Ò ń gbéraga sí Ọlọrun ọ̀run. O ranṣẹ lọ kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun wá siwaju rẹ. Ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ayaba ati àwọn obinrin rẹ, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí waini. Ẹ sì ń yin àwọn oriṣa fadaka, ti wúrà, ti idẹ, ti irin, ti igi ati ti òkúta. Wọn kò ríran wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. O kò yin Ọlọrun tí ẹ̀mí rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀ lógo, ẹni tí ó mọ gbogbo ọ̀nà rẹ. +Ìdí nìyí tí ó fi rán ọwọ́ kan jáde láti kọ àkọsílẹ̀ yìí. +“Ohun tí a kọ náà nìyí: ‘MENE, MENE, TEKELI, PERESINI.’ +Ìtumọ̀ rẹ̀ sì nìyí: MENE, Ọlọrun ti ṣírò àwọn ọjọ́ ìjọba rẹ, ó sì ti parí rẹ̀. +TEKELI, a ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o kò sì kún ojú ìwọ̀n. +PERESINI, a ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mede ati àwọn ará Pasia.” +Beṣasari bá pàṣẹ, pé kí wọ́n gbé ẹ̀wù elése àlùkò, ti àwọn olóyè, wọ Daniẹli, kí wọ́n sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. Wọ́n kéde ká gbogbo ìjọba pé Daniẹli ni igbá kẹta ní ìjọba. +Wọ́n bá kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí wọ́n kó ninu tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí. +Ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an ni wọ́n pa Beṣasari, ọba àwọn ará Kalidea. +Dariusi, ará Mede, ẹni ọdún mejilelọgọta sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. +Bí wọn tí ń mu ọtí, ni wọ́n ń yin ère wúrà, ère fadaka, ère irin, ère igi, ati ère òkúta. +Lẹsẹkẹsẹ, ọwọ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé sí ara ògiri ààfin níbi tí iná fìtílà tan ìmọ́lẹ̀ sí, ọba rí ọwọ́ náà, bí ó ti ń kọ̀wé. +Ojú ọba yipada, ẹ̀rù bà á, ara rẹ̀ ń gbọ̀n, orúnkún rẹ̀ sì ń lu ara wọn. +Ó kígbe sókè pé kí wọ́n tètè lọ pe àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea ati àwọn awòràwọ̀ wá. Nígbà tí wọ́n dé, ọba sọ fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka ohun tí wọ́n kọ sára ògiri yìí, tí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fi aṣọ elése àlùkò dá a lọ́lá, n óo ní kí wọ́n fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, yóo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ninu ìjọba mi.” +Gbogbo àwọn amòye ọba wá, wọn kò lè ka àwọn àkọsílẹ̀ náà, wọn kò sì lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. +Ọkàn Beṣasari dàrú, ojú rẹ̀ yipada. Àwọn ìjòyè rẹ̀ dààmú, wọn kò sì mọ ohun tí wọ́n lè ṣe. +Àsè Beṣasari. +Dariusi ṣètò láti yan ọgọfa (120) gomina láti ṣe àkóso ìjọba rẹ̀. +Nígbà tí Daniẹli gbọ́ pé wọ́n ti fi ọwọ́ sí òfin náà, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó wọ yàrá òkè lọ, ó ṣí fèrèsé ilé rẹ̀ sílẹ̀, sí apá Jerusalẹmu. Ó kúnlẹ̀, ó ń gbadura, ó sì ń yin Ọlọrun, nígbà mẹta lojoojumọ. +Àwọn ọkunrin wọnyi bá kó ara wọn jọ. Wọ́n wá wo Daniẹli níbi tí ó ti ń gbadura, tí ó sì ń bẹ̀bẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ̀. +Wọ́n wá siwaju ọba, wọ́n sọ nípa àṣẹ tí ó pa pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ rẹ̀, ati pé ẹnikẹ́ni tí ó bá rú òfin yìí, a óo jù ú sinu ihò kinniun.Ọba dáhùn, ó ní: “Dájúdájú, òfin Mede ati Pasia ni, tí a kò lè yipada.” +Wọ́n bá sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ìgbèkùn Juda kò kà ọ́ sí, kò sì pa òfin rẹ mọ́. Ṣugbọn ìgbà mẹta lóòjọ́ níí máa gbadura.” +Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ọkàn rẹ̀ dàrú lọpọlọpọ, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ títí ilẹ̀ fi ṣú láti gba Daniẹli sílẹ̀. +Àwọn ọkunrin wọnyi gbìmọ̀, wọ́n sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, o mọ̀ pé òfin Mede ati ti Pasia ni pé òfin tí ọba bá ṣe kò gbọdọ̀ yipada.” +Ọba bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Daniẹli, kí wọ́n sì jù ú sinu ihò kinniun. Ṣugbọn ó sọ fún Daniẹli pé, “Ọlọrun rẹ tí ò ń sìn láìsinmi yóo gbà ọ́.” +Wọ́n yí òkúta dí ẹnu ihò kinniun náà. Ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ sì fi òǹtẹ̀ òrùka wọn tẹ ọ̀dà tí wọ́n yọ́ lé e, kí ẹnikẹ́ni má lè gba Daniẹli sílẹ̀. +Ọba bá lọ sí ààfin rẹ̀, ó fi gbogbo òru náà gbààwẹ̀. Kò jẹ́ kí àwọn eléré ṣe eré níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì lè sùn. +Bí ilẹ̀ ti mọ́, ọba dìde, ó sáré lọ sí ibi ihò kinniun náà. +Ó yan àwọn mẹta láti máa ṣe àbojútó gbogbo wọn, Daniẹli sì jẹ́ ọ̀kan ninu wọn. Àwọn mẹta wọnyi ni àwọn ọgọfa (120) gomina náà yóo máa jábọ̀ fún. +Nígbà tí ó dé ẹ̀bá ibẹ̀, ó kígbe pẹlu ohùn arò, ó ní, “Daniẹli, iranṣẹ Ọlọrun Alààyè, ǹjẹ́ Ọlọrun tí ò ń sìn láìsinmi gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn kinniun?” +Daniẹli dáhùn pé, “Kabiyesi, kí ọba pẹ́, +Ọlọrun mi ti rán angẹli rẹ̀, ó ti dí àwọn kinniun lẹ́nu, wọn kò sì pa mí lára. Nítorí pé n kò jẹ̀bi níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ṣe nǹkan burúkú sí ìwọ ọba.” +Inú ọba dùn pupọ, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n yọ Daniẹli jáde. Wọ́n bá yọ Daniẹli jáde kúrò ninu ihò kinniun, àwọn kinniun kò sì pa á lára rárá, nítorí pé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun rẹ̀. +Ọba bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú gbogbo àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kan Daniẹli, ati àwọn ọmọ wọn, ati àwọn aya wọn, wọ́n bá dà wọ́n sinu ihò kinniun. Kí wọn tó dé ìsàlẹ̀, àwọn kinniun ti bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì fọ́ egungun wọn túútúú. +Dariusi ọba bá kọ ìwé sí gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà tí ó wà ní orí ilẹ̀ ayé ó ní, “Kí alaafia wà pẹlu yín, +mo pàṣẹ pé ní gbogbo ìjọba mi, kí gbogbo eniyan máa wárìrì níwájú Ọlọrun Daniẹli, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ̀.“Nítorí òun ni Ọlọrun Alààyètí ó wà títí ayérayé.Ìjọba rẹ̀ kò lè parun lae,àṣẹ rẹ̀ yóo sì máa wà títí dé òpin. +Ó ń gbani là,ó ń dáni nídè.Ó ń ṣiṣẹ́ àánú tí ó yani lẹ́nu ní ọ̀run ati ní ayé.Òun ni ó gba Daniẹli lọ́wọ́ agbára kinniun.” +Nǹkan sì ń dára fún Daniẹli ní àkókò Dariusi ati Kirusi, àwọn ọba Pasia. +Ṣugbọn Daniẹli tún ta gbogbo àwọn alámòójútó ati gomina náà yọ nítorí ẹ̀mí tí kò lẹ́gbẹ́ tí ó wà ninu rẹ̀. Ọba sì ń gbèrò láti fi gbogbo ọ̀rọ̀ ìjọba lé e lọ́wọ́. +Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina wọnyi ń wá ẹ̀sùn sí Daniẹli lẹ́sẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìjọba, ṣugbọn wọn kò rí ẹ̀sùn kankan tí wọ́n lè kà sí i lẹ́sẹ̀. Wọn kò ká ohunkohun mọ́ ọn lọ́wọ́ nítorí olóòótọ́ eniyan ni. Wọn kò bá àṣìṣe kankan lọ́wọ́ rẹ̀. +Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “A kò ní rí ẹ̀sùn kà sí Daniẹli lẹ́sẹ̀, àfi ohun tí ó bá jẹmọ́ òfin Ọlọrun rẹ̀.” +Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n wí fún un pé “Dariusi ọba, kí ọba pẹ́, +gbogbo àwọn alabojuto, àwọn olórí, àwọn ìgbìmọ̀, ati àwọn gomina kó ara wọn jọ, wọ́n sì fi ohùn ṣọ̀kan pé kí ọba ṣe òfin kan pé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ òun ọba. Ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kabiyesi, kí wọ́n jù ú sinu ihò kinniun. +Nisinsinyii, kabiyesi, ẹ fi ọwọ́ sí òfin yìí, kí ó lè fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òfin Mede ati Pasia tí kò gbọdọ̀ yipada.” +Nítorí náà, Dariusi ọba fi ọwọ́ sí òfin náà, ó sì fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́. +Daniẹli ninu Ihò Kinniun. +Ní ọdún kinni tí Beṣasari jọba ní Babiloni, Daniẹli lá àlá, o sì rí àwọn ìran kan nígbà tí ó sùn lórí ibùsùn rẹ̀. Ó bá kọ kókó ohun tí ó rí lójú àlá náà sílẹ̀. +Iná ń ṣàn jáde bí odò níwájú rẹ̀.Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn tí ń ṣe iranṣẹ fún un,ọ̀kẹ́ àìmọye sì ni àwọn tí wọ́n dúró níwájú rẹ̀.Ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀, a sì ṣí àwọn ìwé sílẹ̀. +“Mo wò yíká nítorí ọ̀rọ̀ ńláńlá tí ìwo kékeré yìí ń fi ẹnu sọ, mo sì rí i tí wọ́n pa ẹranko náà, tí wọ́n sì jó òkú rẹ̀ níná. +Ní ti àwọn ẹranko tí ó kù, a gba àṣẹ wọn, ṣugbọn a dá wọn sí fún àkókò kan, àní fún ìgbà díẹ̀. +“Ninu ìran, lóru, mo rí ẹnìkan tí ó rí bí Ọmọ Eniyan ninu awọsanma, ó lọ sí ọ̀dọ̀ Ẹni Ayérayé náà, ó sì fi ara rẹ̀ hàn níwájú rẹ̀. +A sì fún Ẹni Ayérayé ní àṣẹ, ògo ati ìjọba, pé kí gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà máa sìn ín. Àṣẹ ayérayé tí kò lè yẹ̀ ni àṣẹ rẹ̀, ìjọba rẹ̀ kò sì lè parun. +“Ìran tí mo rí yìí bà mí lẹ́rù pupọ, ọkàn mi sì dààmú. +Mo bá súnmọ́ ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀, mo bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí, ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ó ní, +‘Àwọn ọba ńlá mẹrin tí yóo jẹ láyé ni àwọn ẹranko ńláńlá mẹrin tí o rí. +Ṣugbọn àwọn eniyan mímọ́ Ẹni Gíga Jùlọ yóo gba ìjọba ayé, ìjọba náà yóo jẹ́ tiwọn títí lae, àní títí ayé àìlópin.’ +“Mo tún fẹ́ mọ̀ nípa ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn yòókù, tí ó bani lẹ́rù lọpọlọpọ, tí èékánná rẹ̀ jẹ́ idẹ, tí eyín rẹ̀ sì jẹ́ irin; tí ń jẹ àjẹrun, tí ó ń fọ́ nǹkan túútúú, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù rẹ̀ mọ́lẹ̀. +Ó ní, “Bí mo ti sùn ní alẹ́, mo rí i lójúran pé afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́ láti igun mẹrẹẹrin ayé ń rú omi òkun ńlá sókè. +Mo fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ìwo mẹ́wàá orí rẹ̀, ati ìwo kékeré, tí ó fa mẹta tí ó wà níwájú rẹ̀ tu, tí ó ní ojú, tí ń fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ ńláńlá, tí ó sì dàbí ẹni pé ó ju gbogbo àwọn yòókù lọ. +“Bí mo ti ń wò ó, mo rí i ti ìwo yìí ń bá àwọn eniyan mímọ́ jà, tí ó sì ń ṣẹgun wọn, +títí tí Ẹni Ayérayé fi dé, tí ó dá àwọn ẹni mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ láre; tí ó sì tó àkókò fún àwọn ẹni mímọ́ láti gba ìjọba. +“Ó ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi báyìí pé: ‘Ẹranko kẹrin ni ìjọba kẹrin tí yóo wà láyé, tí yóo sì yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ìyókù. Yóo ṣẹgun gbogbo ayé, yóo tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, yóo sì fọ́ ọ túútúú. +��wọn ìwo mẹ́wàá dúró fún àwọn ọba mẹ́wàá, tí yóo jáde lára ìjọba kẹrin yìí. Ọ̀kan yóo jáde lẹ́yìn wọn, tí yóo yàtọ̀ sí wọn, yóo sì borí mẹta ninu àwọn ọba náà. +Yóo sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹni Gíga Jùlọ, yóo sì dá àwọn eniyan mímọ́, ti Ẹni Gíga Jùlọ lágara. Yóo gbìyànjú láti yí àkókò ati òfin pada. A óo sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún ọdún mẹta ati ààbọ̀. +Ṣugbọn ìdájọ́ yóo bẹ̀rẹ̀, a óo gba àṣẹ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, a óo sì pa á run patapata. +A óo fi ìjọba ati àṣẹ, ati títóbi àwọn ìjọba tí ó wà láyé fún àwọn eniyan mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ, ìjọba ayérayé ni ìjọba wọn yóo jẹ́, gbogbo àwọn aláṣẹ yóo máa sìn ín, wọn yóo sì máa gbọ́ tirẹ̀.’ +“Òpin ọ̀rọ̀ nípa ìran náà nìyí. Ẹ̀rù èrò ọkàn mi bà mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí ojú mi yipada, ṣugbọn inú ara mi ni mo mọ ọ̀rọ̀ náà sí.” +Àwọn ẹranko ńláńlá mẹrin bá jáde láti inú òkun. Ọ̀kan kò jọ̀kan ni àwọn mẹrẹẹrin. +Ekinni dàbí kinniun, ó sì ní ìyẹ́ bíi ti idì. Mò ń wò ó títí tí ìyẹ́ rẹ̀ fi fà tu. A gbé e dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji bí eniyan. Ó sì ń ronú bí eniyan. +“Ẹranko keji dàbí àmọ̀tẹ́kùn, ó gbé ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan sókè. Ó gbé egungun ìhà mẹta há ẹnu, ó wa eyín mọ́ ọn. Mo sì gbọ́ tí ẹnìkan sọ fún un pé, ‘Dìde, kí o sì máa jẹ ẹran sí i.’ +“Bí mo ti ń wò mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó dàbí ẹkùn, òun náà ní ìyẹ́ mẹrin lẹ́yìn. Ó ní orí mẹrin. A sì fún un ní agbára láti jọba. +“Lẹ́yìn èyí, ninu ìran tí mo rí ní òru náà, ẹranko kẹrin tí mo rí jáni láyà, ó bani lẹ́rù, ó sì lágbára pupọ. Ó tóbi, irin sì ni eyín rẹ̀. A máa fọ́ nǹkan túútúú, á jẹ ẹ́ ní àjẹrun, á sì fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀, ìwo mẹ́wàá ni ó ní. +Bí mo ti ń ronú nípa àwọn ìwo rẹ̀, ni mo rí i tí ìwo kékeré kan tún hù láàrin wọn, ìwo mẹta fà tu níwájú rẹ̀ ninu àwọn ìwo ti àkọ́kọ́. Ìwo kékeré yìí ní ojú bí eniyan, ó sì ní ẹnu tí ó fi ń sọ ọ̀rọ̀ ńláńlá. +“Bí mo ti ń wo ọ̀kánkán,mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí a tẹ́.Ẹni Ayérayé sì jókòó lórí ìtẹ́ tirẹ̀,aṣọ rẹ̀ funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú.Irun orí rẹ̀ náà dàbí irun aguntan funfun,ìtẹ́ rẹ̀ ń jó bí ahọ́n iná,kẹ̀kẹ́ abẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sì dàbí iná. +Àlá Daniẹli Nípa Àwọn Ẹranko Mẹrin. +Ní ọdún kẹta tí Beṣasari jọba ni èmi Daniẹli rí ìran kan lẹ́yìn ti àkọ́kọ́. +Ó tóbi pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ń bá àwọn ogun ọ̀run jà, ó já àwọn kan ninu àwọn ìràwọ̀ lulẹ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. +Ó gbé ara rẹ̀ ga, títí dé ọ̀dọ̀ olórí àwọn ogun ọ̀run. Ó gbé ẹbọ sísun ojoojumọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì gba ibi mímọ́ rẹ̀. +A fi ogun náà ati ẹbọ sísun ojoojumọ lé e lọ́wọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀, a sì já òtítọ́ lulẹ̀. Gbogbo ohun tí ìwo náà ń ṣe, ni ó ṣe ní àṣeyọrí. +Ẹni mímọ́ kan sọ̀rọ̀; mo tún gbọ́ tí ẹni mímọ́ mìíràn dá ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ lóhùn pé, “Ìran nípa ẹbọ sísun ojoojumọ yóo ti pẹ́ tó; ati ti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń sọ nǹkan di ahoro; ati ìran nípa pípa ibi mímọ́ tì, ati ti àwọn ọmọ ogun tí wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀?” +Mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ náà dáhùn pé, “Nǹkan wọnyi yóo máa rí báyìí lọ títí fún ẹgbaa ó lé ọọdunrun (2,300) ọdún, lẹ́yìn náà a óo ya ibi mímọ́ sí mímọ́.” +Nígbà tí èmi Daniẹli rí ìran náà, bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mọ ìtumọ̀ rẹ̀, ni ẹnìkan bá yọ níwájú mi tí ó dàbí eniyan. +Mo gbóhùn ẹnìkan láàrin bèbè kinni keji odò Ulai tí ó wí pé, “Geburẹli, sọ ìtumọ̀ ìran tí ọkunrin yìí rí fún un.” +Ó wá sí ẹ̀bá ibi tí mo dúró sí. Bí mo ti rí i, ẹ̀rù bà mí, mo dojúbolẹ̀.Ó bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la ni ohun tí o rí.” +Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo sùn lọ fọnfọn, mo dojúbolẹ̀. Ó bá fọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dìde, +ó ní, “Ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn ibinu Ọlọrun sí àwọn eniyan lẹ́yìn ọ̀la ni ìran tí o rí. +Ninu ìran náà, mo rí i pé mo wà ní Susa, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Elamu. Mo rí i pé mo wà létí odò Ulai. +“Àwọn ọba Pasia ati Media ni àgbò tí o rí, tí ó ní ìwo meji lórí. +Ìjọba Giriki ni òbúkọ onírun jákujàku tí o rí. Ọba àkọ́kọ́ tí yóo jẹ níbẹ̀ ni ìwo ńlá tí ó wà láàrin ojú rẹ̀. +Ìtumọ̀ ìwo tí ó ṣẹ́, tí mẹrin mìíràn sì hù dípò rẹ̀, ni pé lẹ́yìn ikú rẹ̀ ni ìjọba rẹ̀ yóo pín sí mẹrin, ṣugbọn kò ní jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀. +“Nígbà tí ìjọba wọn bá ń lọ sópin, tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn bá kún ojú ìwọ̀n, ọba kan tí ojú rẹ̀ le, tí ó ní àrékérekè, tí ó sì lágbára yóo gorí oyè. +Agbára rẹ̀ yóo pọ̀, ṣugbọn kò ní jẹ́ nípa ipá rẹ̀, yóo máa ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó bá ń ṣe, yóo sì mú kí á run àwọn eniyan Ọlọrun ati àwọn alágbára. +Nípa ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, yóo máa tan àwọn eniyan jẹ, ìgbéraga yóo kún ọkàn rẹ̀, yóo máa pa ọpọlọpọ eniyan lójijì, yóo sì lòdì sí ọba tí ó ju gbogbo àwọn ọba lọ. Ṣugbọn yóo parun láìní ọwọ́ ẹnikẹ́ni ninu. +Ìran ti ẹbọ àṣáálẹ́ ati ti òwúrọ̀ tí a ti là yé ọ yóo ṣẹ dájúdájú; ṣugbọn, pa àṣírí ìran yìí mọ́ nítorí ọjọ́ tí yóo ṣẹ ṣì jìnnà.” +Àárẹ̀ mú èmi Daniẹli, mo sì ṣàìsàn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Nígbà tó yá, mo bá tún dìde, mò ń bá iṣẹ́ tí ọba yàn mí sí lọ, ṣugbọn ìran náà dẹ́rù bà mí, kò sì yé mi. +Bí mo ti gbé ojú sókè, mo rí i tí àgbò kan dúró létí odò, ó ní ìwo meji tí ó ga sókè, ṣugbọn ọ̀kan gùn ju ekeji lọ. Èyí tí ó gùn jù ni ó hù kẹ́yìn. +Mo rí i tí àgbò náà bẹ̀rẹ̀ sí kàn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù, kò sí ẹranko tí ó lè dúró níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ó ti wù ú, ó sì ń gbéraga. +Bí mo tí ń ronú nípa rẹ̀, mo rí i tí òbúkọ kan ti ìhà ìwọ̀ oòrùn la gbogbo ayé kọjá wá láìfi ẹsẹ̀ kan ilẹ̀, ó sì ní ìwo ńlá kan láàrin ojú rẹ̀ mejeeji. +Ó súnmọ́ àgbò tí ó ní ìwo meji, tí mo kọ́ rí tí ó dúró létí odò, ó sì pa kuuru sí i pẹlu ibinu ńlá. +Mo rí i ó súnmọ́ àgbò náà, ó fi tìbínú-tìbínú kàn án, ìwo mejeeji àgbò náà sì ṣẹ́. Àgbò náà kò lágbára láti dúró níwájú rẹ̀. Ó tì í ṣubú, ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. Kò sì sí ẹni tí ó lè gba àgbò náà lọ́wọ́ rẹ̀. +Òbúkọ náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi sí i, ṣugbọn nígbà tí agbára rẹ̀ dé góńgó, ìwo ńlá iwájú rẹ̀ bá kán. Ìwo ńlá mẹrin mìíràn sì hù dípò rẹ̀. Wọ́n kọjú sí ọ̀nà mẹrẹẹrin tí afẹ́fẹ́ ti ń fẹ́ wá. +Lára ọ̀kan ninu àwọn ìwo mẹrin ọ̀hún ni ìwo kékeré kan ti yọ jáde, ó gbilẹ̀ lọ sí ìhà gúsù, sí ìhà ìlà oòrùn ati sí Ilẹ̀ Ìlérí náà. +Ìran tí Daniẹli Rí Nípa Àgbò ati Ewúrẹ́. +Ní ọdún kinni tí Dariusi, ọmọ Ahasu-erusi, ará Mede, jọba ní Babiloni, +A kò gbọ́ tìrẹ OLUWA Ọlọrun wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò pa òfin rẹ tí o fi rán àwọn wolii, iranṣẹ rẹ sí wa mọ́. +Gbogbo Israẹli ti rú òfin rẹ, wọ́n ti pada lẹ́yìn rẹ, wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́ tìrẹ. Nítorí náà, ègún ati ìbúra tí Mose, iranṣẹ rẹ kọ sinu ìwé òfin ti ṣẹ mọ́ wa lára. +Ohun tí o sọ pé o óo ṣe sí àwa ati àwọn ọba wa náà ni o ṣe sí wa, tí àjálù ńlá fi dé bá wa. Irú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu yìí kò ṣẹlẹ̀ sí ìlú kan rí, ninu gbogbo àwọn ìlú ayé yìí. +Gbogbo ìyọnu tí a kọ sinu òfin Mose ti dé bá wa, sibẹ a kò wá ojurere OLUWA Ọlọrun wa, kí á yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí á sì tẹ̀lé ọ̀nà òtítọ́ rẹ̀. +Nítorí náà, OLUWA ti mú kí ìyọnu dé bá wa, ó sì rọ̀jò rẹ̀ lé wa lórí; olódodo ni OLUWA Ọlọrun wa ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, sibẹ a kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀. +“Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun wa, ìwọ tí o kó àwọn eniyan rẹ jáde ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu agbára ńlá, nítorí orúkọ rẹ tí à ń ranti títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe nǹkan burúkú. +OLUWA, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òdodo rẹ, dáwọ́ ibinu ati ìrúnú rẹ dúró lórí Jerusalẹmu, ìlú rẹ, òkè mímọ́ rẹ; nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ ati àìdára àwọn baba wa, ti sọ Jerusalẹmu ati àwọn eniyan rẹ, di àmúpòwe láàrin àwọn tí ó yí wa ká. +Nítorí náà Ọlọrun wa, jọ̀wọ́ gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ. Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, ṣí ojurere wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti di ahoro. +Gbọ́ tiwa, Ọlọrun mi, ṣíjú wò wá, bí àwa ati ìlú tí à ń pe orúkọ rẹ mọ́, ti wà ninu ìsọdahoro. Kì í ṣe nítorí òdodo wa ni a ṣe ń gbadura sí ọ, ṣugbọn nítorí pé aláàánú ni ọ́. +Gbọ́ tiwa, OLUWA, dáríjì wá, tẹ́tí sí wa, OLUWA, wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí, má sì jẹ́ kí ó pẹ́, nítorí orúkọ rẹ, tí a fi ń pe ìlú rẹ ati àwọn eniyan rẹ.” +èmi, Daniẹli bẹ̀rẹ̀ sí ka ọ̀rọ̀ OLUWA, mò ń ronú lórí ohun tí Jeremaya, wolii sọ, pé Jerusalẹmu yóo dahoro fún aadọrin ọdún. +Mo bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, mò ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ èmi ati ti àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, mo kó ẹ̀bẹ̀ mi tọ OLUWA Ọlọrun mi lọ, nítorí òkè mímọ́ rẹ̀. +Bí mo ti ń gbadura, ni Geburẹli, tí mo rí lójúran ní àkọ́kọ́ bá yára fò wá sọ́dọ̀ mi, ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́. +Ó wá ṣe àlàyé fún mi, ó ní, “Daniẹli, àlàyé ìran tí o rí ni mo wá ṣe fún ọ. +Bí o ti bẹ̀rẹ̀ sí gbadura ni àṣẹ dé, òun ni mo sì wá sọ fún ọ́; nítorí àyànfẹ́ ni ọ́. Nisinsinyii, farabalẹ̀ ṣàkíyèsí ọ̀rọ̀ náà, kí òye ìran náà sì yé ọ. +“Ọlọrun ti fi àṣẹ sí i pé, lẹ́yìn aadọrin ọdún lọ́nà meje ni òun óo tó dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan rẹ ati ti ìlú mímọ́ rẹ jì wọ́n, tí òun óo ṣe ètùtù fún ìwà burúkú wọn, tí òun óo mú òdodo ainipẹkun ṣẹ, tí òun óo fi èdìdì di ìran ati àsọtẹ́lẹ̀ náà, tí òun óo sì fi òróró ya Ilé Mímọ́ Jùlọ rẹ̀ sọ́tọ̀. +Mọ èyí, kí ó sì yé ọ, pé láti ìgbà tí àṣẹ bá ti jáde lọ láti tún Jerusalẹmu kọ́, di ìgbà tí ẹni àmì òróró Ọlọrun, tíí ṣe ọmọ Aládé, yóo dé, yóo jẹ́ ọdún meje lọ́nà meje. Lẹ́yìn náà, ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje ni a óo sì fi tún un kọ́, yóo ní òpópónà, omi yóo sì yí i po; ṣugbọn yóo jẹ́ àkókò ìyọnu. +Lẹ́yìn ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje yìí, wọn óo pa ẹni àmì òróró Ọlọrun kan láìṣẹ̀. Àwọn ọmọ ogun alágbára kan tí yóo joyè, yóo pa Jerusalẹmu ati Tẹmpili run. Òpin óo dé bá a bí àgbàrá òjò, ogun ati ìsọdahoro tí a ti fi àṣẹ sí yóo dé. +Ìjòyè yìí yóo bá ọpọlọpọ dá majẹmu ọdún meje tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Fún ìdajì ọdún meje náà, yóo fi òpin sí ẹbọ rírú ati ọrẹ. Olùsọdahoro yóo gbé ohun ìríra ka téńté orí pẹpẹ ní Jerusalẹmu. Ohun ìríra náà yóo sì wà níbẹ̀ títí tí ìgbẹ̀yìn tí Ọlọrun ti fàṣẹ sí yóo fi dé bá olùsọdahoro náà.” +Mo bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ OLUWA Ọlọrun tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ mò ń gbadura tọkàntọkàn pẹlu ààwẹ̀; mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀, mo sì jókòó sinu eérú. +Mo gbadura sí OLUWA Ọlọrun mi, mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi.Mo ní, “OLUWA Ọlọrun, tí ó tóbi, tí ó bani lẹ́rù, tíí máa ń pa majẹmu ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹlu gbogbo àwọn tí ó bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́. +“A ti ṣẹ̀, a ti ṣe burúkú; a ti ṣìṣe, a ti ṣọ̀tẹ̀, nítorí pé a ti kọ òfin ati àṣẹ rẹ sílẹ̀. +A kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn iranṣẹ rẹ, àní àwọn wolii, tí wọ́n wá jíṣẹ́ rẹ fún àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa, àwọn baba wa, ati fún gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà. +Olódodo ni ọ́, OLUWA, ṣugbọn lónìí yìí ojú ti gbogbo àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu, ati gbogbo Israẹli; ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn, níbi gbogbo tí o fọ́n wọn káàkiri sí nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí ọ. +OLUWA, ìtìjú yìí pọ̀ fún àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, ati àwọn baba wa, nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́. +Aláàánú ni ọ́ OLUWA Ọlọrun wa, ò sì máa dáríjì ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. +Daniẹli Gbadura fún Àwọn Eniyan Rẹ̀. +Ọ̀rọ̀ tí Mose bá àwọn eniyan Israẹli sọ ninu aṣálẹ̀ nìyí, ní òdìkejì odò Jọdani, ní Araba tí ó kọjú sí Sufu, láàrin Parani, Tofeli, Labani, Haserotu ati Disahabu. +OLUWA Ọlọrun yín ti sọ yín di pupọ, lónìí ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run. +Kí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín jẹ́ kí ẹ tún pọ̀ jù báyìí lọ lọ́nà ẹgbẹrun. Kí ó sì bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fun yín. +Báwo ni mo ṣe lè dá nìkan dàyàkọ ìnira yín ati ẹrù yín ati ìjà yín. +Mo ní kí ẹ yan àwọn ọlọ́gbọ́n, tí wọ́n ní ìmọ̀ ati ìrírí láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, n óo sì fi wọ́n ṣe olórí yín. +Ìdáhùn tí ẹ fún mi nígbà náà ni pé, ohun tí mo wí ni ó yẹ kí ẹ ṣe. +Mo bá fi mú àwọn olórí olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, àwọn tí wọ́n gbọ́n tí wọ́n sì ní ìrírí, mo yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí fun yín. Mo fi àwọn kan jẹ balogun lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn lórí araadọta eniyan; bẹ́ẹ̀ ni mo fi àwọn ẹlòmíràn jẹ balogun lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá, mo sì fi àwọn kan ṣe olórí ninu gbogbo ẹ̀yà yín. +“Mo pàṣẹ fún àwọn adájọ́ yín nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ àwọn arakunrin yín, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo láàrin eniyan ati arakunrin rẹ̀, tabi àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. +Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́ yín; kì báà jẹ́ àwọn eniyan ńláńlá, kì báà jẹ́ àwọn mẹ̀kúnnù, bákan náà ni kí ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù eniyan, nítorí Ọlọrun ni onídàájọ́. Bí ẹjọ́ kan bá le jù fun yín láti dá, ẹ kó o tọ̀ mí wá, n óo sì dá a.’ +Gbogbo ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe nígbà náà ni mo pa láṣẹ fun yín. +“Gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wa ti pàṣẹ fún wa nígbà náà, a gbéra ní Horebu, a sì la àwọn aṣálẹ̀ ńláńlá tí wọ́n bani lẹ́rù kọjá, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe rí i ní ojú ọ̀nà àwọn agbègbè olókè àwọn ará Amori; a sì dé Kadeṣi Banea. +Ìrìn ọjọ́ mọkanla ni láti Horebu dé Kadeṣi Banea, tí eniyan bá gba ọ̀nà òkè Seiri. +Mo sọ fun yín nígbà náà pé, ẹ ti dé agbègbè olókè àwọn ará Amori, tí OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa, +ilẹ̀ náà ni OLUWA Ọlọrun yín tẹ́ kalẹ̀ níwájú yín yìí, mo ní kí ẹ gbéra, kí ẹ lọ gbà á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín ti sọ fun yín. Mo ní kí ẹ má bẹ̀rù rárá, kí ẹ má sì fòyà. +“Gbogbo yín wá sọ́dọ̀ mi, ẹ sì wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á rán àwọn eniyan lọ ṣiwaju wa, láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè wá jábọ̀ fún wa, kí á lè mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí á tọ̀, ati àwọn ìlú tí ó yẹ kí á wọ̀.’ +“Ọ̀rọ̀ yín dára lójú mi, mo sì yan ọkunrin mejila láàrin yín, ọkunrin kọ̀ọ̀kan láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. +Wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè náà, títí tí wọ́n fi dé àfonífojì Eṣikolu, tí wọ́n sì ṣe amí rẹ̀. +Wọ́n ká ninu èso ilẹ̀ náà bọ̀, wọ́n sì jábọ̀ fún wa pé ilẹ̀ dáradára ni OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa. +“Sibẹsibẹ, ẹ kọ̀, ẹ kò lọ, ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun yín pa fun yín. +Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kùn ninu àgọ́ yín, ẹ ní, ‘Ọlọrun kò fẹ́ràn wa, ni ó ṣe kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, kí ó lè kó wa lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, kí wọ́n sì pa wá run. +Kí ni a fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀? Ojora ti mú wa, nítorí ọ̀rọ̀ tí àwọn arakunrin wa sọ fún wa, tí wọ́n ní àwọn ará ibẹ̀ lágbára jù wá lọ, wọ́n sì ṣígbọnlẹ̀ jù wá lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, odi wọn ga kan ọ̀run, àwọn òmìrán ọmọ Anaki sì wà níbẹ̀!’ +“Mo wí fun yín nígbà náà pé kí ẹ má ṣojo, kí ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín. +Ní ọjọ́ kinni oṣù kọkanla, ní ogoji ọdún tí wọ́n ti kúrò ní Ijipti, ni Mose bá àwọn eniyan Israẹli sọ ohun tí OLUWA pàṣẹ fún un láti sọ fún wọn; +OLUWA Ọlọrun yín tí ń ṣáájú yín ni yóo jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti jà fun yín ní ilẹ̀ Ijipti, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i. +Ninu aṣálẹ̀ ńkọ́? Ṣebí ẹ rí i bí OLUWA Ọlọrun yín ti gbé yín, bí baba tíí gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ tọ̀ títí tí ẹ fi dé ibi tí ẹ wà yìí. +Sibẹsibẹ ẹ kò gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́, +Ọlọrun tí ń lọ níwájú yín ninu ọ̀wọ̀n iná lóru, ati ninu ìkùukùu lọ́sàn-án, láti fi ọ̀nà tí ẹ óo máa tọ̀ hàn yín kí ó lè bá yín wá ibi tí ẹ óo pàgọ́ yín sí. +“OLUWA gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra pé, +ẹnikẹ́ni ninu ìran burúkú náà kò ní fi ojú kan ilẹ̀ dáradára tí òun ti búra pé òun óo fún àwọn baba yín; +àfi Kalebu ọmọ Jefune ni yóo rí i. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni òun óo sì fún ní ilẹ̀ tí ó ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀, nítorí pé, ó fi tọkàntọkàn tẹ̀lé òun. +OLUWA bínú sí èmi pàápàá nítorí tiyín, ó ní èmi náà kò ní dé ibẹ̀. +Joṣua, ọmọ Nuni, tí ń ṣe iranṣẹ òun, ni yóo dé ilẹ̀ náà. Nítorí náà, ó ní kí n mú un lọ́kàn le, nítorí òun ni yóo jẹ́ kí Israẹli gba ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì jogún rẹ̀. +Ọlọrun ní àwọn ọmọ yín kéékèèké, tí kò tíì mọ ire yàtọ̀ sí ibi, àwọn tí ẹ sọ pé wọn yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín, àwọn ni wọn yóo dé ilẹ̀ náà, àwọn ni òun óo sì fi fún, ilẹ̀ náà yóo sì di ìní wọn. +lẹ́yìn tí ó ti ṣẹgun Sihoni, ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni; ati Ogu, ọba àwọn ará Baṣani, tí ń gbé Aṣitarotu ati Edirei. +Ṣugbọn ní tiyín, ó ní kí ẹ yipada, kí ẹ sì máa lọ sinu aṣálẹ̀, ní apá ọ̀nà Òkun Pupa. +“Nígbà náà, ẹ dá mi lóhùn, ẹ ní, ẹ ti ṣẹ̀ sí OLUWA, nítorí náà, ẹ óo dìde, ẹ óo sì lọ jagun, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun ti pa á láṣẹ fun yín. Olukuluku yín bá múra láti jagun, gbogbo èrò yín nígbà náà ni pé kò ní ṣòro rárá láti ṣẹgun àwọn tí wọn ń gbé agbègbè olókè náà. +“OLUWA wí fún mi pé, ‘Kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má gòkè lọ jagun, nítorí pé n kò ní bá wọn lọ; bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn ọ̀tá yóo ṣẹgun wọn.’ +Mo sọ ohun tí OLUWA wí fun yín, ṣugbọn ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́. Ẹ ṣe oríkunkun sí àṣẹ OLUWA, ẹ sì lọ pẹlu ẹ̀mí ìgbéraga. +Àwọn ará Amori tí wọn ń gbé agbègbè olókè náà bá jáde sí yín, wọ́n le yín bí oyin tíí lé ni, wọ́n sì pa yín ní ìpakúpa láti Seiri títí dé Horima. +Nígbà tí ẹ pada dé, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí sọkún níwájú OLUWA, ṣugbọn OLUWA kò gbọ́ tiyín, bẹ́ẹ̀ ni kò fetí sí ẹkún yín. +“Nítorí náà, gbogbo wa wà ní Kadeṣi fún ìgbà pípẹ́. +Ní òdìkejì odò Jọdani, ní apá ìlà oòrùn, ní ilẹ̀ Moabu, ni Mose ti ṣe àlàyé àwọn òfin wọnyi. Ó ní, +“OLUWA Ọlọrun wa sọ fún wa ní Horebu pé, a ti pẹ́ tó ní ẹsẹ̀ òkè náà. +Ó ní kí á dìde, kí á bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí agbègbè olókè ti àwọn ará Amori, ati gbogbo agbègbè tí ó yí wọn ká ní Araba, ní àwọn agbègbè olókè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, ati èyí tí ó wà létí òkun tí wọn ń pè ní Mẹditarenia, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Lẹbanoni, títí dé odò ńlá nnì, àní odò Yufurate. +Ó ní, ‘Ẹ wò ó! Mo ti pèsè ilẹ̀ náà fun yín, ẹ lọ, kí ẹ sì gbà á; Èmi OLUWA ti búra láti fún Abrahamu ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba ńlá yín ati arọmọdọmọ wọn.’ ” +“Mo sọ fun yín nígbà náà pé, èmi nìkan kò ní lè máa ṣe àkóso yín. +Ìwé Karun-un Mose, tí à ń pè ní Diutaronomi. +“OLUWA sọ fún mi pé, ‘Gbẹ́ tabili òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, fi igi kan àpótí kan kí o sì gun orí òkè tọ̀ mí wá. +“Mo wà ní orí òkè fún odidi ogoji ọjọ́ gẹ́gẹ́ bíi ti àkọ́kọ́, OLUWA sì tún gbọ́ ohùn mi, ó gbà láti má pa yín run. +OLUWA wí fún mi pé, ‘Gbéra, kí o máa lọ láti ṣáájú àwọn eniyan náà, kí wọ́n lè lọ gba ilẹ̀ tí mo búra fún wọn pé n óo fún wọn.’ +“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, kò sí ohun tí OLUWA Ọlọrun yín fẹ́ kí ẹ ṣe, àfi pé kí ẹ bẹ̀rù rẹ̀, kí ẹ máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ fẹ́ràn rẹ̀ pẹlu gbogbo ọkàn yín ati ẹ̀mí yín, +kí ẹ sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀, tí mo paláṣẹ fun yín lónìí mọ́, fún ire ara yín. +Wò ó, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ni ọ̀run, ati ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀; +sibẹsibẹ Ọlọrun fẹ́ràn àwọn baba yín tóbẹ́ẹ̀ tí ó yan ẹ̀yin arọmọdọmọ wọn, ó yàn yín láàrin gbogbo eniyan tí ó wà láyé. +Nítorí náà, ẹ gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu, kí ẹ má sì ṣe oríkunkun mọ́. +Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun àwọn ọlọ́run, ati OLUWA àwọn olúwa, Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù ni Ọlọrun yín, kì í ṣe ojuṣaaju, kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. +A máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn aláìníbaba ati àwọn opó. Ó fẹ́ràn àwọn àlejò, a sì máa fún wọn ní oúnjẹ ati aṣọ. +Nítorí náà, ẹ fẹ́ràn àwọn àlejò; nítorí pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ Ijipti rí. +N óo kọ ohun tí mo kọ sí ara àwọn tabili ti àkọ́kọ́ tí o fọ́ sí ara wọn, o óo sì kó wọn sinu àpótí náà.’ +Ẹ bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín; ẹ sìn ín, kí ẹ sì súnmọ́ ọn. Orúkọ rẹ̀ ni kí ẹ máa fi búra. +Òun ni kí ẹ máa yìn, òun ni Ọlọrun yín, tí ó ṣe nǹkan ńláńlá tí ó bani lẹ́rù wọnyi fun yín, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i. +Aadọrin péré ni àwọn baba ńlá yín nígbà tí wọn ń lọ sí ilẹ̀ Ijipti; ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun yín ti sọ yín di pupọ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run. +“Mo bá fi igi akasia kan àpótí kan, mo sì gbẹ́ tabili òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, mo gun orí òkè lọ pẹlu àwọn tabili náà lọ́wọ́ mi. +OLUWA bá kọ àwọn òfin mẹ́wàá tí ó kọ sí ara àwọn tabili àkọ́kọ́ sára àwọn tabili náà, ó sì kó wọn fún mi. Àwọn òfin mẹ́wàá yìí ni OLUWA sọ fun yín lórí òkè láti ààrin iná ní ọjọ́ tí ẹ péjọ sí ẹsẹ̀ òkè náà. +Mo gbéra, mo sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, mo sì kó àwọn tabili náà sinu àpótí tí mo kàn, wọ́n sì wà níbẹ̀ bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi.” +(Àwọn eniyan Israẹli rìn láti Beeroti Benejaakani lọ sí Mosera, ibẹ̀ ni Aaroni kú sí, tí wọ́n sì sin ín sí. Eleasari ọmọ rẹ̀ sì ń ṣe iṣẹ́ alufaa dípò rẹ̀. +Wọ́n gbéra láti ibẹ̀, wọ́n lọ sí Gudigoda. Láti Gudigoda, wọ́n lọ sí Jotibata, ilẹ̀ tí ó kún fún ọpọlọpọ odò t�� ń ṣàn. +Ní àkókò yìí, OLUWA ya àwọn ẹ̀yà Lefi sọ́tọ̀ láti máa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA, ati láti máa dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, ati láti máa yin orúkọ rẹ̀, títí di òní olónìí. +Nítorí náà ni àwọn ẹ̀yà Lefi kò fi ní ìpín tabi ogún pẹlu àwọn arakunrin wọn. OLUWA ni ìpín wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín ti wí fún wọn.) +Mose Tún Gba Òfin. +“Nítorí náà, ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa tẹ̀lé gbogbo ìkìlọ̀ ati ìlànà, ati ìdájọ́, ati òfin rẹ̀ nígbà gbogbo. +Nítorí pé, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà yìí, kò rí bí ilẹ̀ Ijipti níbi tí ẹ ti jáde wá; níbi tí ó jẹ́ pé nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn yín tán, ẹ óo ṣe wahala láti bu omi rin ín, bí ìgbà tí à ń bu omi sí ọgbà ẹ̀fọ́. +Ṣugbọn ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà yìí jẹ́ ilẹ̀ tí ó kún fún òkè ati àfonífojì. Láti ojú ọ̀run ni òjò ti ń rọ̀ sí i. +OLUWA Ọlọrun yín tìkararẹ̀ ni ó ń tọ́jú rẹ̀, tí ó sì ń mójútó o láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún títí dé òpin. +“Tí ẹ bá tẹ̀lé òfin mi tí mo fun yín lónìí, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn ati ẹ̀mí yín, +yóo rọ òjò sórí ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀, ati òjò àkọ́rọ̀ ati ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ baà lè kórè ọkà, ọtí waini, ati òróró olifi yín. +Yóo mú kí koríko dàgbà ninu pápá fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ẹ óo jẹ, ẹ óo sì yó. +Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ̀tàn má baà wọ inú ọkàn yín, kí ẹ má baà yipada sí àwọn oriṣa, kí ẹ sì máa bọ wọ́n. +Kí inú má baà bí Ọlọrun si yín, kí o má baà mú kí òjò dáwọ́ dúró, kí ilẹ̀ yín má sì so èso mọ́; kí ẹ má baà parun kíákíá lórí ilẹ̀ tí OLUWA fun yín. +“Nítorí náà, ohun tí mo sọ fun yín yìí, ẹ pa á mọ́ sinu ọkàn yín. Ẹ fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, ẹ so ó mọ́ ọwọ́ yín gẹ́gẹ́ bí àmì, kí ẹ fi ṣe ọ̀já ìgbàjú, kí ó wà ní agbede meji ojú yín mejeeji. +Kí ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín dáradára, ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ẹ bá jókòó ninu ilé yín ati ìgbà tí ẹ bá ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ati ìgbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn yín ati nígbà tí ẹ bá dìde. +(Kì í ṣe àwọn ọmọ yín tí kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí mò ń sọ ni mò ń bá sọ̀rọ̀); nítorí náà, ẹ máa ṣe akiyesi ìtọ́ni OLUWA Ọlọrun yín, ati títóbi rẹ̀, ati agbára rẹ̀, ati ipá rẹ̀. +Ẹ kọ ọ́ sí ara òpó ìlẹ̀kùn ilé yín ati sí ara ẹnu ọ̀nà àbájáde ilé yín. +Kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun búra fún àwọn baba yín, pé òun yóo fún wọn títí lae, níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá wà lókè. +“Tí ẹ bá ṣọ́ra, tí ẹ sì pa gbogbo òfin tí mo fun yín mọ́, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, +OLUWA yóo lé àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jáde fun yín, ẹ óo sì gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ. +Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀, ẹ̀yin ni ẹ óo ni ín. Ilẹ̀ yín yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Lẹbanoni, ati láti odò Yufurate títí dé Òkun tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. +Kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo lè dojú kọ yín, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ tí ẹ óo máa rìn kọjá, jìnnìjìnnì yín yóo sì máa bò wọ́n, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín. +“Ẹ wò ó, mo gbé ibukun ati ègún kalẹ̀ níwájú yín lónìí. +Ibukun ni fun yín bí ẹ bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí mo fun yín lónìí yìí. +Ṣugbọn ègún ni fun yín bí ẹ kò bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ bá yà kúrò lójú ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fun yín lónìí, tí ẹ bá ń sin àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ rí. +Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú yín dé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ, tí ẹ óo sì gbà, ẹ kéde ibukun náà lórí òkè Gerisimu, kí ẹ sì kéde ègún náà lórí òkè Ebali. +Ẹ ranti gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe ní ilẹ̀ Ijipti sí ọba Farao, ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀. +Òkè Gerisimu ati òkè Ebali wà ní òdìkejì Jọdani, ní ojú ọ̀nà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, ní ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé Araba, ní òdìkejì Giligali, lẹ́bàá igi Oaku More. +Nítorí ẹ óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fi fun yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á tán, tí ẹ̀ ń gbé inú rẹ̀, +ẹ ṣọ́ra, kí ẹ máa tẹ̀lé gbogbo ìlànà ati òfin tí mo fi lélẹ̀ níwájú yín lónìí. +Ẹ ranti ohun tí ó ṣe sí àw���n ọmọ ogun ilẹ̀ Ijipti ati sí àwọn ẹṣin wọn ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn; bí ó ti jẹ́ kí omi Òkun Pupa bò wọ́n mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń le yín bọ̀, ati bí OLUWA ti pa wọ́n run títí di òní olónìí. +Ẹ ranti ohun gbogbo tí ó ṣe fun yín ninu aṣálẹ̀ títí tí ẹ fi dé ìhín; +ati ohun tí ó ṣe sí Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ọmọ ọmọ Reubẹni. Ẹ ranti bí ilẹ̀ ti lanu, tí ó sì gbé wọn mì ati àwọn ati gbogbo ìdílé wọn, ati àgọ́ wọn, ati gbogbo iranṣẹ ati ẹran ọ̀sìn wọn, láàrin gbogbo Israẹli. +Ẹ ti fi ojú rí gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí OLUWA ṣe. +“Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́ kí ẹ lè ní agbára tó láti gba ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ láti gbà. +Kí ẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fún wọn ati àwọn arọmọdọmọ wọn. Ilẹ̀ tí ó lọ́ràá tí ó sì ní ẹ̀tù lójú tí ó kún fún wàrà ati oyin. +Títóbi OLUWA. +“Àwọn ìlànà ati òfin, tí ẹ óo máa tẹ̀lé lẹ́sẹẹsẹ, ní gbogbo ọjọ́ ayé yín ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fi fun yín láti gbà, nìyí: +Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani, tí ẹ sì ń gbé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, nígbà tí ó bá sì fun yín ní ìsinmi, tí ẹ bá bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó yí yín ká, tí ẹ sì wà ní àìléwu, +ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn láti fi ibùgbé rẹ̀ sí nígbà náà, ni kí ẹ kó gbogbo àwọn nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín wa, ẹbọ sísun yín ati àwọn ẹbọ mìíràn, ìdámẹ́wàá yín, ati ọrẹ, ati gbogbo ẹ̀jẹ́ yín tí ẹ bá jẹ́ fún OLUWA. +Ẹ óo sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ati ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin yín, ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà láàrin ìlú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín ninu ilẹ̀ yín. +Ẹ ṣọ́ra, ẹ má máa rú ẹbọ sísun yín níbikíbi tí ẹ bá ti rí. +Ṣugbọn ibi tí OLUWA yín bá yàn láàrin ẹ̀yà yín, ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ sísun yín, kí ẹ sì máa ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fun yín níbẹ̀. +“Ṣugbọn ẹ lè pa iye ẹran tí ó bá wù yín, kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbikíbi tí ẹ bá ń gbé, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín tó. Ẹni tí ó mọ́, ati ẹni tí kò mọ́ lè jẹ ninu ẹran náà bí ìgbà tí eniyan ń jẹ ẹran ẹtu tabi ti àgbọ̀nrín. +Ẹ̀jẹ̀ wọn nìkan ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ, dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí ẹni da omi. +Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu ohun tí o bá jẹ́ ìdámẹ́wàá yín ninu ìlú yín, kì báà ṣe ìdámẹ́wàá ọkà yín, tabi ti ọtí waini, tabi ti òróró, tabi ti àkọ́bí mààlúù, tabi ti ewúrẹ́, tabi ti aguntan, tabi ohunkohun tí ẹ bá fi san ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, tabi ọrẹ àtinúwá yín tabi ọrẹ àkànṣe yín. +Níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn, ni kí ẹ ti jẹ ẹ́; ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín, lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wà ninu ìlú yín. Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe. +Kí ẹ rí i dájú pé, ẹ kò gbàgbé àwọn ọmọ Lefi níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ yín. +Gbogbo ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ óo lé kúrò ti ń sin oriṣa wọn ni kí ẹ wó lulẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà lórí òkè ńlá, ati àwọn tí wọ̀n wà lórí àwọn òkè kéékèèké, ati àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ igi tútù. +“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú kí ilẹ̀ yín pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, tí ẹran bá wù yín jẹ, ẹ lè jẹ ẹran dé ibi tí ó bá wù yín. +Bí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà pupọ sí yín, ẹ mú mààlúù tabi aguntan láti inú agbo ẹran tí OLUWA fi fun yín, kí ẹ pa á bí mo ti pa á láṣẹ fun yín, kí ẹ sì jẹ ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́ láti jẹ láàrin àwọn ìlú yín. +Ati ẹni tí ó mọ́ ati ẹni tí kò mọ́ ni ó lè jẹ ninu ẹran náà bí ìgbà tí eniyan ń jẹ ẹran ẹtu tabi ti àgbọ̀nrín. +Kí ẹ rí i dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nítorí pé ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí wà, ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran pẹlu ẹ̀mí rẹ̀. +Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí omi. +Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín nígbà tí ẹ bá ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú OLUWA. +Ẹ gbọdọ̀ mú àwọn ohun ìyàsímímọ́ tí ẹ ní, ati àwọn ẹ̀jẹ́ yín lọ sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìrúbọ. +Kí ẹ rú ẹbọ sísun yín ati ẹran ati ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ da ẹ̀jẹ̀ ẹbọ yín sórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì jẹ ara ẹran rẹ̀. +Ẹ kíyèsára, kí ẹ rí i dájú pé ẹ pa àwọn ohun tí mo pa láṣẹ fun yín mọ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín títí lae. +“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá pa àwọn orílẹ̀-èdè run níbi gbogbo tí ẹ bá lọ, tí ẹ bá bá wọn jagun tí ẹ gba ilẹ̀ wọn, tí ẹ sì ń gbé ibẹ̀; +Ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ fọ́ gbogbo òpó wọn, ẹ dáná sun àwọn ère oriṣa Aṣera wọn, ẹ gé gbogbo àwọn ère oriṣa wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò níbẹ̀. +ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà ṣìnà, lẹ́yìn tí Ọlọrun bá ti pa wọ́n run tán, kí ẹ má baà bèèrè pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ṣe ń bọ àwọn oriṣa wọn? Kí àwa náà lè máa ṣe bẹ́ẹ̀.’ +Ẹ kò gbọdọ̀ sin OLUWA Ọlọrun yín bí wọn ti ń bọ àwọn oriṣa wọn nítorí oríṣìíríṣìí ohun tí ó jẹ́ ìríra lójú OLUWA ni wọ́n máa ń ṣe. Wọn a máa fi àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin wọn rúbọ sí oriṣa wọn. +“Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fun yín ni kí ẹ fọkàn sí, kí ẹ sì ṣe é, ẹ kò gbọdọ̀ fi kún un, ẹ kò sì gbọdọ̀ mú kúrò ninu rẹ̀. +“Ẹ kò gbọdọ̀ máa sin OLUWA Ọlọrun yín káàkiri bí wọ́n ti ń ṣe. +Ṣugbọn ibi tí OLUWA bá yàn láti gbé ibùjókòó rẹ̀ kà láàrin gbogbo àwọn ẹ̀yà, ibẹ̀ ni kí ẹ máa lọ. +Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú gbogbo ẹbọ sísun yín, ati àwọn ẹbọ yòókù wá, ati ìdámẹ́wàá yín, ati ọrẹ àtinúwá yín, ati ẹ̀jẹ́ yín tí ẹ bá jẹ́ fún OLUWA, ati àkọ́bí mààlúù yín, ati ti aguntan yín. +Ibẹ̀ ni ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín yóo ti jẹun níwájú OLUWA Ọlọrun yín, inú yín yóo sì dùn nítorí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín tí OLUWA ti fi ibukun sí. +“Ẹ kò gbọdọ̀ máa ṣe bí a ti ń ṣe níbí lónìí, tí olukuluku ń ṣe èyí tí ó dára lójú ara rẹ̀. +Nítorí pé ẹ kò tíì dé ibi ìsinmi ati ilẹ̀ ìní tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín. +Ibi Ìjọ́sìn Kanṣoṣo Náà. +“Bí ẹnìkan bá di wolii láàrin yín, tabi tí ó ń lá àlá, tí ń sọ nípa àmì ati iṣẹ́ ìyanu tí yóo ṣẹlẹ̀, +Ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí tí ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde kúrò ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti. +Gbogbo ọmọ Israẹli yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo sì bà wọ́n, ẹnikẹ́ni kò sì ní hu irú ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́ láàrin yín. +“Bí ẹ bá gbọ́, ní ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti máa gbé, pé, +àwọn eniyan lásán kan láàrin yín ń tan àwọn ará ìlú náà jẹ, wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ bọ oriṣa.’ +Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ náà. Bí ó bá jẹ́ pé òtítọ́ ni, tí ó sì dáa yín lójú pé ohun ìríra bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ láàrin yín, +idà ni kí ẹ fi pa àwọn tí wọn ń gbé ìlú náà. Ẹ pa wọ́n run patapata, ati gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀; ẹ fi idà pa gbogbo wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. +Ẹ kó gbogbo ìkógun tí ẹ bá rí ninu ìlú náà jọ sí ààrin ìgboro rẹ̀, kí ẹ sì dáná sun gbogbo rẹ̀ bí ẹbọ sísun sí OLUWA Ọlọrun yín. Ìlú náà yóo di àlàpà títí lae, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ tún un kọ́ mọ́. +Àwọn ìkógun yìí jẹ́ ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan èyíkéyìí ninu wọn kí OLUWA lè yí ibinu gbígbóná rẹ̀ pada, kí ó ṣàánú fun yín, kí ó sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba yín. +Ẹ máa gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin rẹ̀, tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA Ọlọrun yín. +tí gbogbo nǹkan tí ó ń sọ sì ń rí bẹ́ẹ̀; bí ó bá wí pé kí ẹ wá lọ bọ oriṣa mìíràn tí ẹ kò mọ̀ rí, +ẹ kò gbọdọ̀ dá wolii tabi alálàá náà lóhùn, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ń dán yín wò ni, láti mọ̀ bóyá ẹ fẹ́ràn òun tọkàntọkàn. +OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ máa tẹ̀lé, òun ni kí ẹ máa bẹ̀rù. Ẹ máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì máa gbọ́ tirẹ̀; ẹ máa sìn ín, kí ẹ sì súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí. +Ṣugbọn pípa ni kí ẹ pa wolii tabi alálàá náà, nítorí pé ó ń kọ yín láti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú. Ẹ níláti pa olúwarẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ mú kí ẹ kọ ẹ̀yìn sí ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín ti là sílẹ̀ fun yín láti máa rìn, nítorí náà ẹ gbọdọ̀ yọ nǹkan burúkú náà kúrò láàrin yín. +“Bí ẹnikẹ́ni bá ń tàn ọ́ níkọ̀kọ̀ pé kí o lọ bọ oriṣa-koriṣa kan, tí ìwọ tabi àwọn baba rẹ kò bọ rí, olúwarẹ̀ kì báà jẹ́ arakunrin rẹ, tíí ṣe ọmọ ìyá rẹ, tabi ọmọ rẹ, lọkunrin tabi lobinrin, tabi aya rẹ, tí ó dàbí ẹyin ojú rẹ, tabi ọ̀rẹ́ rẹ tí o fẹ́ràn ju ẹ̀mí ara rẹ lọ; +oriṣa yìí kì báà jẹ́ èyí tí ó wà nítòsí, tí àwọn ará agbègbè yín ń bọ, tabi èyí tí ó jìnnà réré, tí àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ òkèèrè ń bọ. +O kò gbọdọ̀ gbọ́ tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ dá a lóhùn. O kò gbọdọ̀ ṣàánú fún un, o kò sì gbọdọ̀ bò ó. +Pípa ni kí o pa á, ìwọ gan-an ni kí o kọ́ sọ òkúta lù ú, kí àwọn eniyan yòókù tó kó òkúta bò ó. +“Ọmọ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara yín lára tabi kí ẹ fá irun yín níwájú nígbà tí ẹ bá ń ṣọ̀fọ̀ ẹni tí ó kú. +Ṣugbọn èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n, nítorí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín. +“Ẹ lè jẹ gbogbo àwọn ẹyẹ tí wọ́n bá mọ́. +Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àwọn ẹyẹ wọnyi: ẹyẹ idì, igún ati idì tí ń jẹ ẹja, +ati àṣá gidi, ati oríṣìíríṣìí àṣá mìíràn, ati igún gidi, ati àwọn oríṣìíríṣìí igún yòókù, +ati oríṣìíríṣìí àwọn ẹyẹ ìwò, +ati ògòǹgò, ati òwìwí, ati ẹ̀lulùú, ati oríṣìíríṣìí àwòdì, +ati òwìwí ńlá, ati òwìwí kéékèèké, ati ògbúgbú, +ati ẹyẹ òfù, ati àkàlà, ati ẹyẹ ìgo, +ati ẹyẹ àkọ̀, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ òòdẹ̀, ati ẹyẹ atọ́ka, ati àdán. +“Gbogbo àwọn kòkòrò tí wọn ń fò jẹ́ aláìmọ́ fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n. +Nítorí pé, ẹni ìyàsọ́tọ̀ ni yín fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA ti yàn yín láti jẹ́ eniyan tirẹ̀ láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé. +Ṣugbọn ẹ lè jẹ gbogbo àwọn ohun tí ó bá ní ìyẹ́, tí wọ́n sì mọ́. +“Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrarẹ̀, ẹ lè fún àwọn àlejò tí ń gbé ààrin yín, kí ó jẹ ẹ́, tabi kí ẹ tà á fún àjèjì, nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ ẹni mímọ́ fún OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ ninu wàrà ọmú ìyá rẹ̀. +“Ẹ gbọdọ̀ san ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko yín ní ọdọọdún. +Ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun ni kí ẹ ti jẹ ìdámẹ́wàá ọkà yín, ati ti ọtí waini yín, ati ti òróró yín, ati àkọ́bí àwọn mààlúù yín, ati ti agbo ẹran yín; kí ẹ lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín nígbà gbogbo. +Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá bukun yín tán, tí ibi tí ó yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà jù fun yín láti ru ìdámẹ́wàá ìkórè oko yín lọ, +ẹ tà á, kí ẹ sì gba owó rẹ̀ sọ́wọ́, kí ẹ kó owó náà lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun. +Ẹ fi owó náà ra ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́, ìbáà ṣe akọ mààlúù, tabi aguntan, tabi ọtí waini, tabi ọtí líle, tabi ohunkohun tí ọkàn yín bá ṣá fẹ́. Ẹ óo jẹ ẹ́ níbẹ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ẹ óo sì máa yọ̀, ẹ̀yin ati ìdílé yín. +“Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà láàrin yín nítorí pé, wọn kò ní ìpín tabi ohun ìní láàrin yín. +Ní òpin ọdún kẹtakẹta, ẹ níláti kó ìdámẹ́wàá ìkórè gbogbo oko yín ti ọdún náà jọ, kí ẹ kó wọn kalẹ̀ ninu gbogbo àwọn ìlú yín. +Kí àwọn ọmọ Lefi, tí wọn kò ní ìpín ati ohun ìní láàrin yín, ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó tí wọ́n wà ninu àwọn ìlú yín jẹ, kí wọ́n sì yó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun yín ninu gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín. +“Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ ohun ìríra. +Àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ nìwọ̀nyí: mààlúù, aguntan, +ewúrẹ́, àgbọ̀nrín ati èsúó ati ìgalà, ati oríṣìí ẹranko igbó kan tí ó dàbí ewúrẹ́, ati ẹranko kan tí wọn ń pè ní Pigarigi, ati ẹfọ̀n, ati ẹtu. +Àwọn ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ wọn là sí meji, tabi tí wọ́n bá ní ìka ẹsẹ̀, tí wọ́n sì ń jẹ àpọ̀jẹ, irú wọn ni kí ẹ máa jẹ. +Ṣugbọn ninu àwọn ẹran tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ ati àwọn tí pátákò ẹsẹ̀ wọn là sí meji tabi tí wọ́n ní ìka ẹsẹ̀, àwọn wọnyi ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: ràkúnmí, ati ehoro ati ẹranko kan tí ó dàbí gara. Àwọn wọnyi ń jẹ àpọ̀j�� lóòótọ́, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ wọn kò là, nítorí náà, wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín. +Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹlẹ́dẹ̀, lóòótọ́ ó ní ìka ẹsẹ̀, ṣugbọn kì í jẹ àpọ̀jẹ, nítorí náà, ó jẹ́ aláìmọ́ fun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fara kan òkú wọn. +“Ninu gbogbo àwọn abẹ̀mí tí ó wà ninu omi, àwọn wọnyi ni kí ẹ máa jẹ: gbogbo àwọn ohun tí ó bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ. +Àṣà Tí A kò Gbọdọ̀ Dá tí A bá ń Ṣọ̀fọ̀. +“Ní ọdún keje-keje ni kí ẹ máa ṣe ìdásílẹ̀. +Ẹ fún un ní ohun tí ẹ bá fẹ́ fún un tọkàntọkàn, kì í ṣe pẹlu ìkùnsínú, nítorí pé, nítorí ìdí èyí ni OLUWA Ọlọrun yín yóo ṣe bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín ati gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé. +Nítorí pé, talaka kò ní tán lórí ilẹ̀ yín, nítorí náà ni mo ṣe ń pàṣẹ fun yín pé kí ẹ lawọ́ sí arakunrin yín, ati sí talaka ati sí aláìní ní ilẹ̀ náà. +“Bí wọ́n bá ta arakunrin yín lẹ́rú fun yín, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, tí ó bá ti jẹ́ Heberu, ọdún mẹfa ni yóo fi sìn yín. Tí ó bá di ọdún keje, ẹ gbọdọ̀ dá a sílẹ̀, kí ó sì máa lọ. +Nígbà tí ẹ bá dá a sílẹ̀ pé kí ó máa lọ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó lọ ní ọwọ́ òfo. +Ẹ gbọdọ̀ fún un ní ẹran ọ̀sìn lọpọlọpọ ati ọkà láti inú ibi ìpakà yín, ati ọtí waini. Bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín tó, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe fún un tó. +Ẹ gbọdọ̀ ranti pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA Ọlọrun yín ni ó rà yín pada; nítorí náà ni mo fi ń pàṣẹ fun yín lónìí. +“Ṣugbọn tí ó bá wí fun yín pé, òun kò ní jáde ninu ilé yín, nítorí pé ó fẹ́ràn ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín, nítorí pé ó dára fún un nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ yín, +ẹ mú ìlutí kan, kí ẹ fi lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn. Yóo sì jẹ́ ẹrukunrin yín títí lae. Bí ó bá sì jẹ́ obinrin ni, bákan náà ni kí ẹ ṣe fún un. +Má jẹ́ kí ó ni ọ́ lára láti dá a sílẹ̀ kí ó sì máa lọ lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí pé, ìdajì owó ọ̀yà alágbàṣe ni ó ti fi ń sìn ọ́, fún odidi ọdún mẹfa. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe. +“Gbogbo àkọ́bí tí ẹran ọ̀sìn bá bí ninu agbo ẹran yín, tí ó bá jẹ́ akọ ni ẹ gbọdọ̀ yà á sọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun. Ẹ kò gbọdọ̀ fi akọ tí ó jẹ́ àkọ́bí ninu agbo mààlúù yín ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ rẹ́ irun àgbò tí ó jẹ́ àkọ́bí aguntan yín. +Bí ẹ óo ṣe máa ṣe ìdásílẹ̀ náà nìyí: ẹnikẹ́ni tí aládùúgbò rẹ̀, tíí ṣe arakunrin rẹ̀, bá jẹ ní gbèsè kò ní gba ohun tí aládùúgbò rẹ̀ jẹ ẹ́ mọ́, nítorí pé, a ti kéde ìdásílẹ̀ tíí ṣe ti OLUWA. +Níbikíbi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn, ni ẹ ti gbọdọ̀ máa jẹ wọ́n níwájú rẹ̀, ní ọdọọdún; ẹ̀yin ati gbogbo ilé yín. +Ṣugbọn bí ó bá ní àbààwọ́n kan, bóyá ó jẹ́ arọ ni, tabi afọ́jú, tabi ó ní àbààwọ́n kankan, ẹ kò gbọdọ̀ fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín, +jíjẹ ni kí ẹ jẹ ẹ́ ní ààrin ìlú yín, ati àwọn tí wọ́n mọ́, ati àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ ni wọ́n lè jẹ ninu rẹ̀, bí ìgbà tí eniyan jẹ ẹran èsúó tabi àgbọ̀nrín ni. +Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nìkan ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ; dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí omi. +Bí ó bá jẹ́ pé àlejò ni ó jẹ ẹni náà ní gbèsè, olúwarẹ̀ lè gbà á, ṣugbọn ohunkohun tí ó bá jẹ́ tiyín, tí ó wà lọ́wọ́ arakunrin yín, ẹ kò gbọdọ̀ gbà á pada. +“Ṣugbọn kò ní sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí yóo jẹ́ talaka, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín, ní ilẹ̀ tí ó fun yín láti gbà, +bí ẹ bá sá ti gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì farabalẹ̀, ti ẹ tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí. +Nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín. Ẹ óo máa yá àwọn orílẹ̀-èdè ni nǹkan, ṣugbọn ẹ kò ní tọrọ lọ́wọ́ wọn. Ẹ óo máa jọba lórí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ṣugbọn wọn kò ní jọba lórí yín. +“Bí ẹnìkan ninu yín, tí ó jẹ́ arakunrin yín, bá jẹ́ talaka, tí ó sì wà ninu ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí ó wà ninu ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ dijú sí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ háwọ́ sí arakunrin yín tí ó jẹ́ talaka yìí. +Ẹ gbọdọ̀ lawọ́ sí i, kí ẹ sì yá a ní ohun tí ó tó láti tán gbogbo àìní rẹ̀, ohunkohun tí ó wù kí ó lè jẹ́. +Ẹ ṣọ́ra, kí èròkerò má baà gba ọkàn yín, kí ẹ wí pé, ọdún keje tí�� ṣe ọdún ìdásílẹ̀ ti súnmọ́ tòsí, kí ojú yín sì le sí arakunrin yín tí ó jẹ́ talaka, kí ẹ má sì fún un ní ohunkohun. Kí ó má baà ké pe OLUWA nítorí yín, kí ó sì di ẹ̀ṣẹ̀ si yín lọ́rùn. +Ọdún Keje. +“Ẹ máa ranti láti máa ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá fún OLUWA Ọlọrun yín ninu oṣù Abibu nítorí ninu oṣù Abibu ni ó kó yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, lálẹ́. +Nígbà náà, ẹ óo ṣe àsè àjọ ọ̀sẹ̀, tíí ṣe àjọ̀dún ìkórè fún OLUWA Ọlọrun yín; pẹlu ọrẹ àtinúwá. Ẹ óo mú ọrẹ náà wá bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín. +Ẹ óo máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé àwọn ìlú yín; àwọn àlejò, àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà láàrin yín. +Ẹ ranti pé ẹ ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ lè máa tẹ̀lé àwọn ìlànà wọnyi. +“Ọjọ́ meje ni ẹ gbọdọ̀ máa fi se àsè àjọ̀dún àgọ́ nígbà tí ẹ bá kó ọkà yín jọ láti ibi ìpakà, tí ẹ kó ọtí waini yín jọ láti ibi ìfúntí. +Ẹ máa yọ̀, bí ẹ ti ń gbádùn àjọ̀dún yín, ẹ̀yin, ati àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin ati àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin yín, àwọn ọmọ Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà ní àwọn ìlú yín. +Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi se àsè yìí fún OLUWA Ọlọrun yín níbi tí OLUWA bá yàn pé kí ẹ ti máa jọ́sìn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun gbogbo èso yín, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ óo láyọ̀ gidigidi. +“Ìgbà mẹta láàrin ọdún kan ni gbogbo àwọn ọkunrin yín yóo máa farahàn níwájú OLUWA níbi tí OLUWA bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun; àkókò àjọ̀dún burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati àkókò àjọ̀dún ìkórè, ati àkókò àjọ̀dún àgọ́. Wọn kò gbọdọ̀ farahàn níwájú OLUWA ní ọwọ́ òfo. +Olukuluku ọkunrin yóo mú ọrẹ wá gẹ́gẹ́ bí ó bá ti fẹ́ ati gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun un. +“Ẹ yan àwọn adájọ́ ati àwọn olórí tí OLUWA Ọlọrun yín fi fun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà yín, ní àwọn ìlú yín, wọn yóo sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn eniyan. +Ẹ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju, ẹ kò sì gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀; nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ ọlọ́gbọ́n lójú, a sì máa yí ẹjọ́ aláre pada sí ẹ̀bi. +Ẹ níláti máa rú ẹbọ àjọ ìrékọjá sí OLUWA Ọlọrun yín láti inú agbo mààlúù yín, tabi agbo aguntan yín, níbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun. +Ẹ̀tọ́ nìkan ṣoṣo ni kí ẹ máa ṣe, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ sì lè jogún ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín. +“Ẹ kò gbọdọ̀ gbin igikígi bí igi oriṣa Aṣera sí ẹ̀bá pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, nígbà tí ẹ bá ń kọ́ ọ. +Ẹ kò sì gbọdọ̀ ri òpó mọ́lẹ̀ kí ẹ máa bọ ọ́, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín kórìíra wọn. +Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu pẹlu ẹbọ náà; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà. Oúnjẹ náà jẹ́ oúnjẹ ìpọ́njú, nítorí pé ìkánjú ni ẹ fi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti; ẹ óo sì lè máa ranti ọjọ́ náà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. +Wọn kò gbọdọ̀ bá ìwúkàrà lọ́wọ́ yín, ati ní gbogbo agbègbè yín, fún ọjọ́ meje. Ẹran tí ẹ bá fi rúbọ kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kinni, títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. +“Ẹ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ àjọ ìrékọjá láàrin èyíkéyìí ninu àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi fun yín. +Àfi ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, níbẹ̀ ni ẹ ti gbọdọ̀ máa rú ẹbọ àjọ ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀ ní àkókò tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. +Bíbọ̀ ni kí ẹ bọ̀ ọ́, kí ẹ jẹ ẹ́ ní ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa jọ́sìn, nígbà tí ó bá sì di òwúrọ̀ ẹ óo pada lọ sinu àgọ́ yín. +Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní ọjọ́ keje, ẹ óo pe àpèjọ tí ó ní ọ̀wọ̀, ẹ óo sì sin OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà. +“Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ tí ẹ kọ́kọ́ ti dòjé bọ inú oko ọkà, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí gé e. +Àjọ Ìrékọjá. +“Ẹ kò gbọdọ̀ fi mààlúù tabi aguntan tí ó ní àbààwọ́n rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín nítorí pé ohun ìríra ni ó jẹ́ fún un. +Ohunkohun tí wọ́n bá sọ fun yín ní ibi tí OLUWA bá yàn ni ẹ gbọdọ̀ ṣe. Ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá ní kí ẹ ṣe. +Ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fun yín ni kí ẹ gbà, kí ẹ sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà tí wọ́n bá là sílẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ yà sí ọ̀tún tabi sí òsì ninu ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fun yín. +Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe oríkunkun sí ẹni tí ó jẹ́ onídàájọ́ nígbà náà, tabi alufaa tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò náà, pípa ni kí ẹ pa á; bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ohun burúkú náà kúrò láàrin Israẹli. +Gbogbo àwọn eniyan ni yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo bà wọ́n; ẹnikẹ́ni kò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. +“Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, tí ẹ bá gbà á, tí ẹ sì ń gbé inú rẹ̀, tí ẹ bá wí nígbà náà pé, ‘A óo fi ẹnìkan jọba lórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n yí wa ká,’ +ẹ lè fi ẹnikẹ́ni tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn fun yín jọba, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín ni ẹ gbọdọ̀ fi jọba, ẹ kò gbọdọ̀ fi àlejò, tí kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín jọba. +Ṣugbọn kò gbọdọ̀ máa kó ẹṣin jọ fún ara rẹ̀ tabi kí ó mú kí àwọn eniyan náà pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti láti ra ẹṣin kún ẹṣin, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti wí fun yín pé, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ sí ibẹ̀ mọ́.’ +Kò gbọdọ̀ kó aya jọ kí ọkàn rẹ̀ má baà yipada; bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kó wúrà ati fadaka jọ fún ara rẹ̀. +“Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó gba ìwé òfin yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa ọmọ Lefi, kí ó dà á kọ sinu ìwé kan fún ara rẹ̀. +Kí ẹ̀dà àwọn òfin yìí máa wà pẹlu rẹ̀, kí ó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; kí ó lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun rẹ̀, nípa pípa gbogbo òfin ati ìlànà wọnyi mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn; +“Bí ọkunrin kan tabi obinrin kan láàrin àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín bá ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA Ọlọrun yín, nípa pé ó da majẹmu rẹ̀, +kí ó má baà rò ninu ara rẹ̀ pé òun ga ju àwọn arakunrin òun lọ, kí ó má baà yipada sí ọ̀tún tabi sí òsì kúrò ninu òfin OLUWA, kí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ lè pẹ́ lórí oyè ní Israẹli. +bí ó bá lọ bọ oriṣa, kì báà ṣe oòrùn, tabi òṣùpá, tabi ọ̀kan ninu àwọn nǹkan mìíràn tí ó wà ní ojú ọ̀run, tí mo ti pàṣẹ pé ẹ kò gbọdọ̀ bọ; +bí wọn bá sọ fun yín tabi ẹ gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí. Bí ó bá jẹ́ pé òtítọ́ ni, tí ìdánilójú sì wà pé ohun ìríra bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ní Israẹli, +ẹ mú ẹni tí ó ṣe ohun burúkú náà jáde lọ sí ẹnu ibodè yín, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa. +Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta kí wọ́n tó lè pa ẹnikẹ́ni fún irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ pa eniyan nítorí ẹ̀rí ẹnìkan ṣoṣo. +Àwọn ẹlẹ́rìí ni wọ́n gbọdọ̀ kọ́kọ́ sọ òkúta lu ẹni náà, lẹ́yìn náà ni gbogbo eniyan yóo tó kó òkúta bò ó, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín. +“Bí ẹjọ́ kan bá ta kókó tí ó ní àríyànjiyàn ninu, tí ó sì ṣòro láti dá fún àwọn onídàájọ́ yín, kì báà jẹ mọ́ ṣíṣèèṣì paniyan ati mímọ̀ọ́nmọ̀ paniyan, tabi ẹ̀tọ́ lórí ohun ìní ẹni; tabi tí ẹnìkan bá ṣe ohun àbùkù kan sí ẹlòmíràn, ẹ óo lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín yóo yàn, pé kí ẹ ti máa jọ́sìn. +Ẹ tọ àwọn alufaa ọmọ Lefi lọ, kí ẹ sì kó ẹjọ́ yín lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó wà ní ipò onídàájọ́ ní àkókò náà. Ẹ ro ẹjọ́ yín fún wọn, wọn yóo sì bá yín dá a. +Ìkìlọ̀ nípa Yíyan Ọba. +“Gbogbo ẹ̀yà Lefi ni alufaa, nítorí náà wọn kò ní bá àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù pín ilẹ̀. Ninu ọrẹ fún ẹbọ sísun, ati àwọn ọrẹ mìíràn tí àwọn eniyan Israẹli bá mú wá fún OLUWA, ni àwọn ẹ̀yà Lefi yóo ti máa jẹ. +Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, kì báà ṣe ọmọ rẹ̀ obinrin tabi ọkunrin. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ máa wo iṣẹ́ kiri tabi kí ó di aláfọ̀ṣẹ tabi oṣó; +tabi kí ó máa sa òògùn sí ẹlòmíràn, tabi kí ó máa bá àwọn àǹjọ̀nú sọ̀rọ̀, tabi kí ó di abókùúsọ̀rọ̀. +Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi di ohun ìríra níwájú OLUWA, ati pé nítorí ohun ìríra wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín ṣe ń lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fun yín. +Gbogbo ìwà ati ìṣe yín níláti jẹ́ èyí tí ó tọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun yín. +“Àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ óo gba ilẹ̀ wọn yìí a máa ṣe àyẹ̀wò, wọn a sì máa gbọ́ ti àwọn aláfọ̀ṣẹ, ṣugbọn ní tiyín, OLUWA Ọlọrun yín kò gbà fun yín pé kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀. +OLUWA Ọlọrun yín yóo gbé wolii kan dìde tí yóo dàbí mi láàrin yín, tí yóo jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín, òun ni kí ẹ máa gbọ́ràn sí lẹ́nu. +“Bíi ti ọjọ́ tí ẹ péjọ ní òkè Horebu tí ẹ bẹ OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sọ fún mi pé, ‘Má jẹ́ kí á gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa mọ́, tabi kí á rí iná ńlá yìí mọ́; kí á má baà kú.’ +OLUWA wí fún mi nígbà náà pé, ‘Gbogbo ohun tí wọ́n sọ patapata ni ó dára. +N óo gbé wolii kan dìde gẹ́gẹ́ bíì rẹ, láàrin àwọn arakunrin wọn, n óo fi ọ̀rọ̀ mi sí i lẹ́nu, yóo sì máa sọ ohun gbogbo tí mo bá pa láṣẹ fún wọn. +Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí yóo máa sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra mi ni n óo jẹ olúwarẹ̀ níyà. +Wọn kò ní ní ìpín láàrin àwọn arakunrin wọn. OLUWA ni ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn. +Ṣugbọn wolii tí ó bá fi orúkọ mi jẹ́ iṣẹ́ tí n kò rán an, tabi tí ó jẹ́ iṣẹ́ kan fun yín ní orúkọ àwọn oriṣa, wolii náà gbọdọ̀ kú ni.’ +“Bí ẹ bá ń rò ninu ọkàn yín pé, báwo ni ẹ óo ti ṣe mọ ìgbà tí wolii kan bá ń jẹ́ iṣẹ́ tí Ọlọrun kò rán an. +Nígbà tí wolii kan bá jíṣẹ́ ní orúkọ OLUWA, bí ohun tí ó sọ pé yóo ṣẹlẹ̀ kò bá ṣẹlẹ̀, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó rán an; wolii náà ń dá iṣẹ́ ara rẹ̀ jẹ́ ni, ẹ má bẹ̀rù rẹ̀. +“Ohun tí yóo jẹ́ ti àwọn alufaa lára ẹran tí àwọn eniyan bá fi rúbọ nìyí, kì báà jẹ́ akọ mààlúù tabi aguntan ni wọ́n wá fi rúbọ, wọn yóo fún alufaa ní apá ati ẹ̀rẹ̀kẹ́ mejeeji, ati àpòlùkú rẹ̀. +Kí ẹ fún àwọn alufaa ní àkọ́so oko yín, ati àkọ́pọn ọtí waini yín, ati àkọ́ṣe òróró yín, ati irun aguntan tí ẹ bá kọ́kọ́ rẹ́. +Nítorí ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ẹ̀yà Lefi ati ti arọmọdọmọ wọn ni OLUWA Ọlọrun yín ti yàn láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún un. +“Bí ọ̀kan ninu ẹ̀yà Lefi bá dìde láti ilé rẹ̀, tabi ibikíbi tí ó wù kí ó ti wá ní Israẹli, tabi ìgbà yòówù tí ó bá fẹ́ láti wá sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìsìn rẹ̀, +ó lè ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ níwájú OLUWA. +Bákan náà ni wọn yóo jọ pín oúnjẹ wọn láìka ohun tí àwọn ará ilé rẹ̀ bá fi ranṣẹ sí i gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó kàn án ninu ogún baba rẹ̀ tí wọ́n tà. +“Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìwà ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń hù. +Ìpín Àwọn Alufaa. +“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá pa àwọn orílẹ̀-èdè tí yóo fun yín ní ilẹ̀ wọn run, tí ẹ bá gba ilẹ̀ wọn, tí ẹ sì ń gbé inú àwọn ìlú wọn, ati ilé wọn, +Kí ẹnikẹ́ni má baà ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti jogún, kí ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ má baà wà lórí yín. +“Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá kórìíra aládùúgbò rẹ̀, tí ó bá ba dè é, tí ó mọ̀ọ́nmọ̀ pa á, tí ó sì sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi, +kí àwọn àgbààgbà ìlú rán ni lọ mú ẹni náà wá, kí wọ́n sì fi lé ẹni tí yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa lọ́wọ́, kí ó lè pa ẹni tí ó mọ̀ọ́nmọ̀ paniyan yìí. +Ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú rẹ̀ rárá, ṣugbọn ẹ níláti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò láàrin Israẹli, kí ó lè dára fun yín. +“Ninu ogún tìrẹ tí ó bá kàn ọ́ ninu ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti gbà, o kò gbọdọ̀ sún ohun tí àwọn baba ńlá rẹ bá fi pààlà ilẹ̀. +“Ẹ̀rí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo péré kò tó láti fi dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi lórí ẹ̀sùnkẹ́sùn tí wọ́n bá fi kàn án, tabi ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ tí ó bá ṣẹ̀. Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta, kí ẹ tó lè dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi lórí ẹ̀sùn kan. +Bí ẹlẹ́rìí èké kan bá dìde láti jẹ́rìí èké mọ́ ẹnìkan, tí ó bá fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ṣe nǹkan burúkú, +kí àwọn mejeeji tí wọn ń ṣe àríyànjiyàn yìí wá siwaju OLUWA, níwájú àwọn alufaa ati àwọn tí wọ́n jẹ́ onídàájọ́ nígbà náà. +Kí àwọn onídàájọ́ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí bí ọ̀rọ̀ ti rí, bí wọ́n bá rí i pé ẹ̀rí èké ni ọkunrin yìí ń jẹ́, tabi pé ẹ̀sùn èké ni ó fi kan arakunrin rẹ̀; +ohun tí ó fẹ́ kí wọ́n ṣe fún arakunrin rẹ̀ gan an ni kí ẹ ṣe fún òun náà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú nǹkan burúkú kúrò láàrin yín. +ẹ ya ìlú mẹta sọ́tọ̀ fún ara yín ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín. +Àwọn yòókù yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo bà wọ́n, wọn kò sì ní ṣe irú nǹkan burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́ láàrin yín. +Ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú olúwarẹ̀ rárá, tó bá jẹ́ pé ó fẹ́ kí wọ́n pa arakunrin rẹ̀ ni, pípa ni kí ẹ pa òun náà; bí ó bá jẹ́ ẹyinjú tabi eyín rẹ̀ ni ó fẹ́ kí wọ́n yọ, ẹ yọ ojú tabi eyín ti òun náà; bí ó bá sì jẹ́ pé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ó fẹ́ kí wọ́n gé, ẹ gé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ ti òun náà. +Ẹ pín ilẹ̀ náà sí agbègbè mẹta, kí ẹ sì la ọ̀nà mẹta wọ inú àwọn ìlú náà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ìlú mẹtẹẹta tí ẹ yà sọ́tọ̀ gbọdọ̀ wà ní agbègbè kọ̀ọ̀kan. Ẹ óo sì ṣí àwọn ọ̀nà tí ó wọ ìlú wọnyi kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè tètè sálọ sibẹ. +Èyí wà fún anfaani ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan. Bí ẹnìkan bá ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti ń bá ara wọn ṣe ọ̀tá tẹ́lẹ̀, bí ó bá sálọ sí èyíkéyìí ninu àwọn ìlú náà, yóo gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. +Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá lọ sinu igbó pẹlu aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó ti ń fi àáké gé igi lọ́wọ́, bí irin àáké náà bá yọ, tí ó lọ bá aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì pa á; irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú náà, kí ó sì gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. +Kí ó má jẹ́ pé, nígbà tí ẹni tí yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ṣèèṣì pa bá ń lé e lọ pẹlu ibinu, bí ibi tí yóo sá àsálà lọ bá jìnnà jù, yóo bá a, yóo sì pa á; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ kí wọ́n pa ẹni tí ó ṣèèṣì paniyan yìí, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé òun ati aládùúgbò rẹ̀ kìí ṣe ọ̀tá tẹ́lẹ̀. +Nítorí náà ni mo fi pàṣẹ fun yín pé, ẹ níláti ya ìlú mẹta sọ́tọ̀. +“Bí OLUWA Ọlọrun yín bá sì mú kí ilẹ̀ yín tóbi síi gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba yín, tí ó bá fun yín ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún àwọn baba yín, +bí ẹ bá lè pa gbogbo òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí mọ́, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, nígbà náà, ẹ tún fi ìlú mẹta mìíràn kún àwọn ìlú mẹta ti àkọ́kọ́. +Àwọn ìlú Ààbò. +“Nígbà tí ó yá, a pada sinu aṣálẹ̀ ní ọ̀nà Òkun Pupa, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún mi; a sì rìn káàkiri lórí òkè Seiri fún ọpọlọpọ ọjọ́. +(Ìran àwọn òmìrán kan tí à ń pè ní Emimu ní ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Wọ́n pọ̀, wọ́n sì lágbára. Wọ́n ṣígbọnlẹ̀ bí àwọn ọmọ Anaki. +Wọn a máa pè wọ́n ní Refaimu gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Anakimu, ṣugbọn àwọn ará Moabu ń pè wọ́n ní Emimu. +Àwọn ará Hori ni wọ́n ń gbé òkè Seiri tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn àwọn ọmọ Esau ti gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì ti pa wọ́n run. Wọ́n bá tẹ̀dó sórí ilẹ̀ àwọn ọmọ Hori gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli náà ti tẹ̀dó sórí ilẹ̀ tí wọ́n gbà, tí OLUWA fún wọn.) +“Ẹ dìde nisinsinyii kí ẹ sì kọjá sí òdìkejì odò Seredi. A sì ṣí lọ sí òdìkejì odò Seredi. +Lẹ́yìn ọdún mejidinlogoji gbáko tí a ti kúrò ní Kadeṣi Banea, ni a tó kọjá odò Seredi, títí tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun ún jà ninu ìran náà fi run tán patapata, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti búra pé yóo rí. +OLUWA dójúlé wọn nítòótọ́ títí gbogbo wọn fi parun patapata ninu ibùdó àwọn ọmọ Israẹli. +“Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun-ún jà ti kú tán láàrin àwọn ọmọ Israẹli, +OLUWA bá wí fún mi pé, +‘Òní ni ọjọ́ tí ẹ óo ré ààlà àwọn ará Moabu kọjá ní Ari. +Nígbà tí ẹ bá súnmọ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Amoni, ẹ má ṣe dà wọ́n láàmú, ẹ má sì bá wọn jagun, nítorí pé n kò ní fun yín ní ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ìní, nítorí pé, àwọn ọmọ Lọti ni mo ti fún.’ ” +“OLUWA bá wí fún mi pé, +(Ibẹ̀ ni wọ́n ń pè ní ilẹ̀ Refaimu, nítorí pé, àwọn Refaimu ni wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn àwọn ará Amoni a máa pè wọ́n ní Samsumimu. +Àwọn tí à ń pè ní Refaimu yìí pọ̀, wọ́n lágbára, wọ́n sì ṣígbọnlẹ̀ bí àwọn ọmọ Anaki, àwọn òmìrán. Ṣugbọn OLUWA pa wọ́n run fún àwọn ará Amoni, wọ́n gba ilẹ̀ wọn, wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ. +Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe fún àwọn ọmọ Esau tí wọn ń gbé òkè Seiri nígbà tí ó pa àwọn ará Hori run fún wọn, tí àwọn ọmọ Esau gba ilẹ̀ wọn, tí wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ títí di òní olónìí, ni ó ṣe fún àwọn ará Amoni. +Àwọn ará Afimu ni wọ́n ti ń gbé àwọn ìletò tí wọ́n wà títí dé Gasa tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn àwọn kan tí wọ́n wá láti Kafitori ni wọ́n pa wọ́n run, tí wọ́n sì tẹ̀dó sí ilẹ̀ wọn.) +“Ẹ dìde, ẹ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò yín, kí ẹ sì ré àfonífojì Anoni kọjá. Mo ti fi Sihoni, ọba Heṣiboni, ní ilẹ̀ àwọn ará Amori, le yín lọ́wọ́, àtòun ati ilẹ̀ rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí bá a jagun, kí ẹ sì máa gba ilẹ̀ rẹ̀. +Láti òní lọ, n óo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé yìí, tí wọ́n bá gbúròó yín, wọn yóo máa gbọ̀n, ojora yóo sì mú wọn nítorí yín. +“Nítorí náà mo rán àwọn oníṣẹ́ láti aṣálẹ̀ Kedemotu, sí Sihoni, ọba Heṣiboni. Iṣẹ́ alaafia ni mo rán sí i, mo ní, +‘Jẹ́ kí n kọjá láàrin ilẹ̀ rẹ. Ojú ọ̀nà tààrà ni n óo máa gbà lọ. N kò ní yà sí ọ̀tún tabi sí òsì. +Rírà ni n óo ra oúnjẹ tí n óo jẹ lọ́wọ́ rẹ, n óo sì ra omi tí n óo mu pẹlu. Ṣá ti gbà mí láàyè kí n kọjá, +bí àwọn ọmọ Esau, tí wọn ń gbé Seiri ati àwọn ará Moabu tí wọn ń gbé Ari, ti ṣe fún mi, títí tí n óo fi kọjá odò Jọdani, lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wa ti fi fún wa.’ +‘Ìrìn tí ẹ rìn káàkiri ní agbègbè olókè yìí tó gẹ́ẹ́; ẹ yipada sí apá àríwá.’ +“Ṣugbọn Sihoni, ọba Heṣiboni kọ̀ fún wa, kò jẹ́ kí á kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí OLUWA Ọlọrun yín mú kí ọkàn rẹ̀ le, ó sì mú kí ó ṣe oríkunkun, kí ó lè fi le yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe lónìí. +“OLUWA sọ fún mi pé, ‘Wò ó, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí fi Sihoni ati ilẹ̀ rẹ̀ le yín lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí gbà á, kí ẹ lè máa gbé ibẹ̀.’ +Sihoni bá jáde sí wa, òun ati àwọn eniyan rẹ̀, láti bá wa jagun ní Jahasi. +OLUWA Ọlọrun wa fi lé wa lọ́wọ́, a ṣẹgun rẹ̀, ati òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. +A gba àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ nígbà náà, a sì run wọ́n, ati ọkunrin, ati obinrin, ati àwọn ọmọ wọn. A kò dá ohunkohun sí, +àfi àwọn ohun ọ̀sìn tí a kó bí ìkógun, pẹlu àwọn ìkógun tí a kó ninu àwọn ìlú tí a gbà. +Láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni lọ, ati ìlú ńlá tí ó wà ní àfonífojì, títí dé Gileadi, kò sí ìlú tí ó ju agbára wa lọ. OLUWA Ọlọrun wa fi gbogbo wọn lé wa lọ́wọ́, +àfi ilẹ̀ àwọn ọmọ Amoni nìkan ni ẹ kò súnmọ́, àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní etí odò Jaboku, ati àwọn ìlú ńláńlá tí ó wà ní agbègbè olókè, ati gbogbo ibi tí OLUWA Ọlọrun wa ti paláṣẹ pé a kò gbọdọ̀ dé. +OLUWA ní kí n pàṣẹ pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹ óo là kọjá yìí jẹ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Esau, àwọn arakunrin yín, tí wọn ń gbé òkè Seiri. Ẹ̀rù yín yóo máa bà wọ́n, nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi; +ẹ má bá wọn jà, nítorí n kò ní fun yín ní ilẹ̀ wọn, bí ó ti wù kí ó kéré tó. Mo ti fi gbogbo ilẹ̀ Edomu ní òkè Seiri fún arọmọdọmọ Esau, gẹ́gẹ́ bí ìní wọn. +Ẹ óo ra oúnjẹ jẹ lọ́wọ́ wọn, ẹ óo sì ra omi mu lọ́wọ́ wọn.’ +“Ẹ ranti bí OLUWA Ọlọrun yín ti bukun yín ninu gbogbo ohun tí ẹ dáwọ́lé, ó sì ti tọ́jú yín ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀ ń rìn kiri ninu aṣálẹ̀ ńláńlá yìí. Ó ti wà pẹlu yín láti ogoji ọdún sẹ́yìn wá, ohunkohun kò sì jẹ yín níyà. +“A bá kọjá lọ láàrin àwọn arakunrin wa, àwọn ọmọ Esau tí wọn ń gbé òkè Seiri, a ya ọ̀nà tí ó lọ láti Elati ati Esiongeberi sí Araba sílẹ̀. A yipada a sì gba ọ̀nà aṣálẹ̀ Moabu. +OLUWA sọ fún mi pé, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ da àwọn ará Moabu láàmú, tabi kí ẹ gbógun tì wọ́n; nítorí pé n kò fun yín ní ilẹ̀ wọn, nítorí pé mo ti fi ilẹ̀ Ari fún àwọn ọmọ Lọti gẹ́gẹ́ bí ohun ìní wọn.’ ” +Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Sihoni Ọba. +“Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, tí ẹ bá rí ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín, tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wà pẹlu yín. +“Bí ẹ bá ti súnmọ́ ìlú tí ẹ fẹ́ bá jagun, ẹ kọ́ rán iṣẹ́ alaafia sí wọn. +Bí wọ́n bá rán iṣẹ́ alaafia pada, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn wọn fun yín, kí ẹ kó gbogbo àwọn ará ìlú náà lẹ́rú kí wọ́n sì máa sìn yín. +Ṣugbọn bí wọ́n bá kọ̀, tí àwọn náà dìde ogun si yín, ẹ dó ti ìlú náà. +Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi ìlú náà le yín lọ́wọ́, kí ẹ fi idà pa gbogbo àwọn ọkunrin t�� wọ́n wà níbẹ̀. +Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn obinrin ati àwọn ọmọ wọn sí, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo dúkìá yòókù tí ó wà ninu ìlú náà, kí ẹ kó gbogbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín, kí ẹ máa lo gbogbo dúkìá àwọn ọ̀tá yín tí OLUWA Ọlọrun yín ti fun yín. +Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sí àwọn ìlú tí ó jìnnà sí yín, tí kì í ṣe àwọn ìlú orílẹ̀-èdè tí ó wà níhìn-ín. +“Ṣugbọn gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ninu àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi fun yín, gẹ́gẹ́ bí ìní yín, ẹ kò gbọdọ̀ dá ohun alààyè kan sí ninu wọn. +Rírun ni kí ẹ run gbogbo wọn patapata, gbogbo àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Kenaani, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi; gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín ti pa á láṣẹ. +Kí wọ́n má baà kọ yín ní ìkọ́kúkọ̀ọ́, kí ẹ má baà máa ṣe oríṣìíríṣìí àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń bọ àwọn oriṣa wọn, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín. +“Nígbà tí ẹ bá dó ti ìlú kan fún ìgbà pípẹ́, tí ẹ bá ń bá ìlú náà jagun tí ẹ fẹ́ gbà á, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ́ àwọn igi eléso wọn lulẹ̀ ní ìbẹ́kúbẹ̀ẹ́. Jíjẹ ni kí ẹ máa jẹ èso igi wọn, ẹ kò gbọdọ̀ gé wọn lulẹ̀. Àbí eniyan ni igi inú igbó, tí ẹ óo fi máa gbé ogun tì í? +Nígbà tí ẹ bá súnmọ́ ojú ogun, kí alufaa jáde kí ó sì bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, kí ó wí fún wọn pé, +Àwọn igi tí ẹ bá mọ̀ pé èso wọn kìí ṣe jíjẹ nìkan ni kí ẹ máa gé, kí ẹ máa fi ṣe àtẹ̀gùn, tí ẹ fi lè wọ ìlú náà, títí tí ọwọ́ yín yóo fi tẹ̀ ẹ́. +‘Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, tí ẹ̀ ń lọ sí ojú ogun lónìí láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àyà yín já, ẹ̀rù kò sì gbọdọ̀ bà yín, ẹ kò gbọdọ̀ wárìrì tabi kí ẹ jẹ́ kí jìnnìjìnnì dà bò yín. +Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ati láti fun yín ní ìṣẹ́gun.’ +“Lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀gágun yóo wí fún àwọn eniyan náà pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ilé titun, tí kò tíì yà á sí mímọ́? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ ya ilé rẹ̀ sí mímọ́, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo ya ilé rẹ̀ sí mímọ́. +Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbin ọgbà àjàrà, tí kò sì tíì jẹ ninu èso rẹ̀? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo jẹ èso ọgbà àjàrà rẹ̀. +Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ iyawo sọ́nà tí kò tíì gbé e wọlé? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada lọ sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo fẹ́ iyawo rẹ̀.’ +“Àwọn ọ̀gágun yóo tún bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ẹ̀rù ń bà, tabi tí àyà rẹ̀ ń já? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé, kí ó má baà kó ojora bá àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.’ +Nígbà tí àwọn ọ̀gágun bá parí ọ̀rọ̀ tí wọn ń bá àwọn eniyan náà sọ, wọn óo yan àwọn kan tí wọn óo máa ṣe aṣaaju ìsọ̀rí-ìsọ̀rí àwọn jagunjagun. +Ọ̀rọ̀ nípa Ogun. +“Bí ẹ bá rí òkú eniyan tí wọ́n pa sinu igbó, lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, tí ẹ kò sì mọ ẹni tí ó pa á, +“Nígbà tí ẹ bá lọ bá àwọn ọ̀tá yín jagun, tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi wọ́n le yín lọ́wọ́, tí ẹ bá sì kó wọn lẹ́rú; +tí ẹ bá rí arẹwà obinrin kan láàrin àwọn ẹrú náà tí ó wù yín láti fi ṣe aya fún ara yín. +Ẹ mú un wá sí ilẹ̀ yín ẹ fá irun orí rẹ̀, kí ẹ sì gé èékánná ọwọ́ rẹ̀. +Ẹ bọ́ aṣọ ẹrú rẹ̀ sílẹ̀, kí ó wà ní ilẹ̀ yín, kí ó sì máa ṣọ̀fọ̀ baba ati ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan. Lẹ́yìn náà ẹ lè wọlé tọ̀ ọ́, kí ẹ sì di tọkọtaya. +Lẹ́yìn náà, tí kò bá wù yín mọ́ ẹ níláti fún un láyè kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá wù ú, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ tà á bí ẹrú, ẹ kò sì gbọdọ̀ lò ó ní ìlò ẹrú, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bá a lòpọ̀ rí. +“Bí ẹnìkan bá ní iyawo meji, tí ó fẹ́ràn ọ̀kan, tí kò sì fẹ́ràn ekeji, tí àwọn mejeeji bímọ fún un, tí ó bá jẹ́ pé iyawo tí kò fẹ́ràn ni ó bí àkọ́bí ọmọkunrin rẹ̀ fún un, +ní ọjọ́ tí yóo bá ṣe ètò bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóo ṣe pín ogún rẹ̀, kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju, kí ó pín ogún fún ọmọ ẹni tí ó fẹ́ràn gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí, kí �� sì ṣe ọmọ ẹni tí kò fẹ́ràn bí ẹni pé kì í ṣe òun ni àkọ́bí rẹ̀. +Ṣugbọn kí ó fihàn pé ọmọ obinrin tí òun kò fẹ́ràn yìí ni àkọ́bí òun, kí ó sì fún un ní ogún tí ó tọ́ sí i ninu ohun ìní rẹ̀. Òun ṣá ni àkọ́bí rẹ̀, òun sì ni ẹ̀tọ́ àkọ́bí tọ́ sí. +“Bí ẹnìkan bá bí ọmọkunrin kan, tí ó jẹ́ aláìgbọràn ati olórí kunkun ọmọ, tí kì í gbọ́, tí kì í sì í gba ti àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n bá a wí títí, ṣugbọn tí kò gbọ́, +kí baba ati ìyá rẹ̀ mú un wá siwaju àwọn àgbààgbà ìlú náà, ní ẹnu bodè ìlú tí ó ń gbé, +kí àwọn àgbààgbà ati àwọn adájọ́ yín jáde wá, kí wọ́n wọn ilẹ̀ láti ibi tí wọ́n pa ẹni náà sí títí dé gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká ibẹ̀. +kí wọ́n wí fún àwọn àgbààgbà ìlú náà pé, ‘Ọmọ wa yìí ya olóríkunkun ati aláìgbọràn, kì í gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Oníjẹkújẹ ati onímukúmu sì ni.’ +Lẹ́yìn náà kí àwọn ọkunrin ìlú sọ ọ́ ní òkúta pa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó ṣe yọ ibi kúrò láàrin yín; gbogbo Israẹli yóo gbọ́, wọn yóo sì bẹ̀rù. +“Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ kan, tí ó jẹ́ pé ikú ni ìjìyà irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ẹ bá so ó kọ́ sórí igi, +òkú rẹ̀ kò gbọdọ̀ sun orí igi náà. Ẹ níláti sin ín ní ọjọ́ náà, nítorí ẹni ìfibú Ọlọrun ni ẹni tí a bá so kọ́ orí igi, ẹ kò gbọdọ̀ sọ ilẹ̀ yín tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín di aláìmọ́. +Kí àwọn àgbààgbà ìlú tí ó bá súnmọ́ ibẹ̀ jùlọ wá ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan tí ẹnikẹ́ni kò tíì so àjàgà mọ́ lọ́rùn láti fi ṣiṣẹ́ rí, +kí wọ́n mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù náà lọ sí àfonífojì tí ó ní odò tí ń ṣàn, tí ẹnikẹ́ni kò gbin ohunkohun sí rí, kí wọ́n sì lọ́ ọ̀dọ́ mààlúù náà lọ́rùn pa níbẹ̀. +Kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, bá wọn lọ pẹlu; nítorí àwọn ni OLUWA Ọlọrun yín yàn láti máa ṣe alufaa ati láti máa súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA; ati pé àwọn ni OLUWA Ọlọrun yàn láti parí àríyànjiyàn ati ẹjọ́. +Kí gbogbo àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà ní ìlú náà wẹ ọwọ́ wọn sórí mààlúù tí wọ́n ti lọ́ lọ́rùn pa yìí. +Kí wọ́n wí pé, ‘A kò lọ́wọ́ ninu ikú ọkunrin yìí, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ ẹni tí ó pa á. +OLUWA, dáríjì Israẹli, àwọn eniyan rẹ, tí o ti rà pada, má sì ṣe jẹ àwọn eniyan Israẹli níyà nítorí ikú aláìṣẹ̀ yìí. Ṣugbọn dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ náà jì wọ́n.’ +Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe wẹ ara yín mọ́ kúrò ninu ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀, bí ẹ bá ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA. +Tí Ikú Ẹnìkan Bá Rúni lójú. +“Ẹ kò gbọdọ̀ máa wo mààlúù tabi aguntan arakunrin yín, kí ó máa ṣìnà lọ, kí ẹ sì mójú kúrò, ẹ níláti fà á tọ olówó rẹ̀ lọ. +“Ẹ kò gbọdọ̀ so àjàgà kan náà mọ́ akọ mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́rùn, láti fi wọ́n ṣiṣẹ́ ninu oko. +“Ẹ kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí wọ́n bá pa irun pọ̀ mọ́ òwú hun. +“Ẹ gbọdọ̀ fi oko wọnjanwọnjan sí igun mẹrẹẹrin aṣọ ìbora yín. +“Bí ẹnìkan bá gbé ọmọge níyàwó, ṣugbọn tí ó kórìíra rẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti bá a lòpọ̀, +tí ó wá sọ pé ó ti ṣe ìṣekúṣe, tí ó sì fi bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ ní orúkọ burúkú, tí ó bá wí pé, ‘Mo gbé obinrin yìí níyàwó ṣugbọn nígbà tí mo súnmọ́ ọn, n kò bá a nílé.’ +“Kí baba ati ìyá ọmọbinrin yìí mú aṣọ ìbálé rẹ̀ jáde, kí wọ́n sì mú un tọ àwọn àgbààgbà ìlú náà lọ ní ẹnubodè. +Kí baba ọmọ náà wí fún wọn pé, ‘Mo fi ọmọbinrin mi yìí fún ọkunrin yìí ní aya, lẹ́yìn tí ó ti bá a lòpọ̀ tán, +ó fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ti ṣe ìṣekúṣe. Ó ní, “N kò bá ọmọ rẹ nílé.” ’ Kí baba ọmọbinrin tẹ́ aṣọ ìbálé rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àwọn àgbààgbà, kí ó sì wí pé, ‘Èyí ni ẹ̀rí pé ó bá ọmọ mi nílé.’ +Àwọn àgbààgbà ìlú náà yóo mú ọkunrin yìí, wọn yóo nà án dáradára. +Wọn yóo sì gba ọgọrun-un ìwọ̀n ṣekeli fadaka lọ́wọ́ rẹ̀ fún baba ọmọbinrin náà bíi owó ìtanràn; nítorí pé ó ti bá ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin Israẹli lórúkọ jẹ́. Obinrin náà yóo sì tún jẹ́ iyawo rẹ̀, kò sì gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. +Bí ibi tí olówó ẹran ọ̀sìn yìí ń gbé bá jìnnà jù, tabi tí ẹ kò bá mọ ẹni náà, ẹ níláti fa ẹran ọ̀sìn náà wálé, kí ó sì wà lọ́dọ̀ yín títí tí olówó rẹ̀ yóo fi máa wá a kiri. Nígbà tí ó bá ń wá a, ẹ níláti dá a pada fún un. +“Ṣugbọn bí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan obinrin náà bá jẹ́ òtítọ́, pé wọn kò bá a nílé, +Wọn yóo fa obinrin náà lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé baba rẹ̀, àwọn ọkunrin ìlú yóo sì sọ ọ́ ní òkúta pa, nítorí pé ó ti hu ìwà òmùgọ̀ ní Israẹli níti pé ó ṣe àgbèrè ní ilé baba rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín. +“Bí ọwọ́ bá tẹ ọkunrin kan ní ibi tí ó ti ń bá iyawo oníyàwó lòpọ̀, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa àwọn mejeeji; ati ọkunrin ati obinrin náà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín. +“Bí ẹnìkan bá rí ọmọge kan, tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà láàrin ìlú, tí ó sì bá a lòpọ̀, +ẹ mú àwọn mejeeji jáde wá sí ẹnubodè ìlú, kí ẹ sì sọ wọ́n ní òkúta pa. Ẹ̀ṣẹ̀ ti obinrin ni pé, nígbà tí wọ́n kì í mọ́lẹ̀ láàrin ìlú, kò pariwo kí aládùúgbò gbọ́. Ẹ̀ṣẹ̀ ti ọkunrin ni pé, ó ba àfẹ́sọ́nà arakunrin rẹ̀ jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín. +“Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé ninu igbó ni ọkunrin kan ti ki ọmọbinrin kan tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà ẹnìkan mọ́lẹ̀, tí ó sì bá a lòpọ̀, ọkunrin nìkan ni kí wọ́n pa. +Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun sí ọmọbinrin náà, kò jẹ̀bi ikú rárá, nítorí ọ̀rọ̀ náà dàbí pé kí ọkunrin kan pàdé aládùúgbò rẹ̀ kan lójú ọ̀nà, kí ó sì lù ú pa. +Nítorí pé, inú igbó ni ó ti kì í mọ́lẹ̀. Bí ọmọbinrin àfẹ́sọ́nà yìí tilẹ̀ ké: ‘Gbà mí! Gbà mí!’ Kò sí ẹnikẹ́ni nítòsí tí ó lè gbà á sílẹ̀. +“Bí ọkunrin kan bá rí ọmọbinrin kan, tí kì í ṣe àfẹ́sọ́nà ẹnikẹ́ni, tí ó kì í mọ́lẹ̀, tí ó sì bá a lòpọ̀, bí ọwọ́ bá tẹ̀ wọ́n, +ọkunrin tí ó bá obinrin yìí lòpọ̀ níláti fún baba ọmọbinrin náà ní aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Ọmọbinrin yìí yóo sì di iyawo rẹ̀, nítorí pé ó ti fi ipá bá a lòpọ̀, kò sì gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. +Bákan náà ni ẹ níláti ṣe, tí ó bá jẹ́ pé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ni ó sọnù, tabi aṣọ rẹ̀, tabi ohunkohun tí ó bá jẹ́ ti arakunrin yín, tí ó bá sọnù tí ẹ sì rí i. Ẹ kò gbọdọ̀ mójú kúrò bí ẹni pé ẹ kò rí i. +“Ọkunrin kò gbọdọ̀ fi èyíkéyìí ninu àwọn aya baba rẹ̀ ṣe aya, tabi kí ó bá a lòpọ̀. +“Ẹ kò gbọdọ̀ máa wo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi akọ mààlúù arakunrin yín, tí ó wó lulẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà, kí ẹ sì mójú kúrò bí ẹni pé ẹ kò rí i. Ẹ níláti ràn án lọ́wọ́ láti gbé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi akọ mààlúù rẹ̀ dìde. +“Obinrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí ó bá jẹ́ ti ọkunrin, bẹ́ẹ̀ sì ni ọkunrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí ó bá jẹ́ ti obinrin nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìríra ni ó jẹ́ lójú OLUWA Ọlọrun yín. +“Bí ẹ bá rí ìtẹ́ ẹyẹ lórí igi tabi ní ilẹ̀, tí ẹyin tabi ọmọ bá wà ninu rẹ̀, tí ìyá ẹyẹ yìí bá ràdọ̀ bò wọ́n, tabi tí ó bá sàba lé ẹyin rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ ẹyẹ náà pẹlu ìyá wọn. +Ẹ níláti fi ìyá wọn sílẹ̀ kí ó máa lọ ṣugbọn ẹ lè kó àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pẹ́ láyé. +“Tí ẹ bá kọ́ ilé titun, ẹ níláti ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ̀ yípo, kí ẹ má baà wá di ẹlẹ́bi bí ẹnikẹ́ni bá jábọ́ láti orí òrùlé yín, tí ó sì kú. +“Ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sáàrin àwọn àjàrà tí ẹ bá gbìn sinu ọgbà àjàrà yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àjàrà náà, ati ohun tí ẹ gbìn sáàrin rẹ̀ yóo di ti ibi mímọ́. +Òfin nípa Ìbálòpọ̀ Ọkunrin ati Obinrin. +“Ọkunrin tí wọ́n bá tẹ̀ lọ́dàá, tabi tí wọ́n bá gé nǹkan ọkunrin rẹ̀, kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ. +Bí ọkunrin kan bá wà ninu yín tí ó di aláìmọ́ nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i láàrin òru, kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kúrò ninu àgọ́. Kò gbọdọ̀ wọ inú àgọ́ wá mọ́. +Ṣugbọn nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́, kí ó wẹ̀. Nígbà tí oòrùn bá sì wọ̀, ó lè wọ inú àgọ́ wá. +“Ẹ gbọdọ̀ ní ibìkan lẹ́yìn àgọ́ tí ẹ óo máa yàgbẹ́ sí. +Kí olukuluku yín ní ọ̀pá kan, tí yóo máa dì mọ́ ara ohun ìjà rẹ̀, tí ó lè fi gbẹ́lẹ̀ nígbà tí ó bá fẹ́ yàgbẹ́; nígbà tí ó bá sì yàgbẹ́ tán, ọ̀pá yìí ni yóo fi wa erùpẹ̀ bò ó mọ́lẹ̀. +Nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín wà pẹlu yín ninu àgọ́ láti gbà yín là, ati láti jẹ́ kí ọwọ́ yín tẹ àwọn ọ̀tá yín. Nítorí náà, àgọ́ yín níláti jẹ́ mímọ́, kí OLUWA má baà rí ohunkohun tí ó jẹ́ àìmọ́ láàrin yín, kí ó sì yipada kúrò lọ́d��̣ yín. +“Bí ẹrú kan bá sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, tí ó bá tọ̀ yín wá, ẹ kò gbọdọ̀ lé e pada sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. +Ẹ jẹ́ kí ó máa bá yín gbé, kí ó wà láàrin yín ninu èyíkéyìí tí ó bá yàn ninu àwọn ìlú yín. Ibi tí ó bá wù ú ni ó lè gbé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ni ín lára. +“Ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan Israẹli, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di alágbèrè ní ilé oriṣa kankan. +Ọkunrin tabi obinrin kankan kò gbọdọ̀ mú owó tí ó bá gbà ní ibi àgbèrè ṣíṣe wá sinu ilé OLUWA láti san ẹ̀jẹ́kẹ́jẹ̀ẹ́ tí ó bá jẹ́, nítorí pé, àgbèrè ṣíṣe jẹ́ ohun ìríra níwájú OLUWA Ọlọrun yín. +“Tí ẹ̀yin ọmọ Israẹli bá yá ara yín lówó, tabi oúnjẹ tabi ohunkohun, ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé lórí rẹ̀. +“Ọmọ àlè kankan kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ, arọmọdọmọ rẹ̀ títí dé ìran kẹwaa kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ. +Bí ẹ bá yá àlejò ní nǹkan, ẹ lè gba èlé, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ yá arakunrin yín ní ohunkohun kí ẹ sì gba èlé, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà. +“Nígbà tí ẹ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbọdọ̀ má san ẹ̀jẹ́ náà, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ yín, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn bí ẹ kò bá san án. +Ṣugbọn tí ẹ kò bá jẹ́jẹ̀ẹ́ rárá, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fun yín. +Níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá ti fínnúfẹ́dọ̀ jẹ́jẹ̀ẹ́ ohunkohun fún OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ti fi ẹnu yín ṣèlérí, ẹ sì níláti rí i pé, ẹ mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ. +“Nígbà tí ẹ bá ń kọjá lọ ní ibi ọgbà àjàrà ẹlòmíràn, ẹ lè jẹ ìwọ̀nba èso àjàrà tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ mú ẹyọkan lọ́wọ́ lọ. +Nígbà tí ẹ bá ń kọjá lọ ní oko ọkà ẹlòmíràn, tí wọn kò tíì kórè, ẹ lè fi ọwọ́ ya ìwọ̀nba tí ẹ lè jẹ, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ fi dòjé gé ọkà ọlọ́kà. +“Ará Amoni ati Moabu kankan kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ, arọmọdọmọ wọn títí dé ìran kẹwaa kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ; +nítorí pé, nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, wọn kò gbé oúnjẹ ati omi pàdé yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, Balaamu ọmọ Beori ará Petori, ní Mesopotamia, ni wọ́n bẹ̀ pé kí ó wá gbé yín ṣépè. +Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín kò fetí sí ti Balaamu, ó yí èpè náà sí ìre fun yín nítorí pé ó fẹ́ràn yín. +Ẹ kò gbọdọ̀ ro ire kàn wọ́n tabi kí ẹ wá ìtẹ̀síwájú wọn títí lae. +“Ẹ kò gbọdọ̀ kórìíra àwọn ọmọ Edomu, nítorí pé arakunrin yín ni wọ́n. Ẹ kò gbọdọ̀ kórìíra àwọn ará Ijipti nítorí pé ẹ ti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ wọn rí. +Bẹ̀rẹ̀ láti ìran kẹta wọn, wọ́n lè bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ. +“Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jagun, tí ẹ bá sì wà ninu àgọ́, ẹ níláti yẹra fún ohunkohun tíí ṣe ibi. +Yíyọ Orúkọ Eniyan kúrò ninu Orúkọ Àwọn Eniyan OLUWA. +“Bí ọkunrin kan bá fẹ́ iyawo, tí iyawo náà kò bá wù ú mọ́ nítorí pé ó rí ohun àléébù kan ninu ìwà rẹ̀ tí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn; tí ó bá já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí obinrin náà jáde kúrò ní ilé rẹ̀, tí obinrin náà sì bá tirẹ̀ lọ; +“Tí ẹ bá yá ẹnìkejì yín ní nǹkankan, ẹ kò gbọdọ̀ wọ ilé rẹ̀ lọ láti wá ohun tí yóo fi dógò. +Ìta ni kí ẹ dúró sí, kí ẹ sì jẹ́ kí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un wá fun yín. +Bí ó bá jẹ́ aláìní ni olúwarẹ̀, aṣọ tí ó bá fi dógò kò gbọdọ̀ sùn lọ́dọ̀ yín. +Ẹ gbọdọ̀ dá a pada fún un ní alẹ́, kí ó lè rí aṣọ fi bora sùn, kí ó lè súre fun yín. Èyí yóo jẹ́ ìwà òdodo lójú OLUWA Ọlọrun yín. +“Ẹ kò gbọdọ̀ rẹ́ alágbàṣe yín tí ó jẹ́ talaka ati aláìní jẹ, kì báà jẹ́ ọmọ Israẹli ẹlẹgbẹ́ yín, tabi àlejò tí ó ń gbé ọ̀kan ninu àwọn ìlú yín. +Lojoojumọ, kí oòrùn tó wọ̀, ni kí ẹ máa san owó iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ fún un, nítorí pé ó nílò owó yìí, kò sì sí ohun mìíràn tí ó gbẹ́kẹ̀lé. Bí ẹ kò bá san án fún un, yóo ké pe OLUWA, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn. +“Ẹ kò gbọdọ̀ pa baba dípò ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọdọ̀ pa ọmọ dípò baba, olukuluku ni yóo kú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá dá. +“Ẹ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò tabi aláìníbaba po, bẹ́ẹ̀ sì ni, tí ẹ bá yá opó ní ohunkohun, ẹ kò gbọdọ̀ gba aṣọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò. +Ṣugbọn ẹ ranti pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, ati pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó rà yín pada níbẹ̀, nítorí náà ni mo fi ń pàṣẹ fun yín láti ṣe èyí. +“Nígbà tí ẹ bá ń kórè ọkà ninu oko yín, tí ẹ bá gbàgbé ìdì ọkà kan sinu oko, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ gbé e. Ẹ fi sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín. +bí obinrin yìí bá lọ ní ọkọ mìíràn, +Bí ẹ bá ti ká èso olifi yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó. +Bí ẹ bá ti ká èso àjàrà yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn opó ati àwọn aláìní baba. +Ẹ ranti pé ẹ ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, nítorí náà ni mo fi pàṣẹ fun yín láti ṣe èyí. +ṣugbọn tí kò tún wu ọkọ titun náà, tí òun náà tún já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí ó sì tún tì í jáde kúrò ninu ilé rẹ̀, tabi tí ọkọ keji tí obinrin yìí fẹ́ bá kú, +ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ kò gbọdọ̀ gbà á pada mọ́ nítorí pé obinrin náà ti di aláìmọ́. Ohun ìríra ni èyí lójú OLUWA. Ẹ kò gbọdọ̀ dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín. +“Bí ọkunrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbeyawo, kò gbọdọ̀ jáde lọ sí ojú ogun tabi kí á fún un ní iṣẹ́ ìlú ṣe, ó gbọdọ̀ wà ní òmìnira ninu ilé rẹ̀ fún ọdún kan gbáko, kí ó máa faramọ́ iyawo rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́. +“Bí ẹnikẹ́ni bá yá eniyan ní nǹkankan, kò gbọdọ̀ gba ọlọ tabi ọmọ ọlọ tí ẹni náà fi ń lọ ọkà gẹ́gẹ́ bíi ìdógò, nítorí pé bí ó bá gba èyíkéyìí ninu mejeeji, bí ìgbà tí ó gba ẹ̀mí eniyan ni. +“Bí ẹnìkan bá jí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ gbé, tí ó sì ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ẹrú, tabi tí ó tà á, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa olúwarẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ohun burúkú yìí kúrò láàrin yín. +“Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú yín, ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì rí i pé ẹ ṣe gbogbo ohun tí àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá là sílẹ̀ fun yín láti ṣe, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún wọn. +Ẹ ranti ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe sí Miriamu nígbà tí ẹ̀ ń jáde ti ilẹ̀ Ijipti bọ̀. +Kíkọ Iyawo sílẹ̀ ati Títún Igbeyawo ṣe. +“Bí èdè-àìyedè kan bá bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ meji, tí wọ́n bá lọ sí ilé ẹjọ́, tí àwọn adájọ́ sì dá ẹjọ́ náà fún wọn, tí wọ́n dá ẹni tí ó jàre láre, tí wọ́n sì dá ẹni tí ó jẹ̀bi lẹ́bi, +Wọn yóo sì máa pe ìdílé rẹ̀ ní ìdílé ẹni tí wọ́n bọ́ bàtà lẹ́sẹ̀ rẹ̀. +“Bí ọkunrin meji bá ń jà, tí iyawo ọ̀kan ninu wọn bá sáré wá láti gbèjà ọkọ rẹ̀ tí wọn ń lù, tí ó bá fa nǹkan ọkunrin ẹni tí ń lu ọkọ rẹ̀ yìí, +gígé ni kí ẹ gé ọwọ́ rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú rẹ̀ rárá. +“O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí ìwọ̀n meji ninu àpò rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi. +O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí òṣùnwọ̀n meji ninu ilé rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi. +Ṣugbọn ìwọ̀n ati òṣùnwọ̀n rẹ gbọdọ̀ péye, kí ọjọ́ rẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ. +Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe aiṣootọ, ìríra ni lójú OLUWA Ọlọrun yín. +“Ẹ ranti ohun tí àwọn ará Amaleki ṣe sí yín nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti Ijipti. +Wọn kò bẹ̀rù Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n gbógun tì yín lójú ọ̀nà nígbà tí ó ti rẹ̀ yín, wọ́n sì pa gbogbo àwọn tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn. +Nítorí náà nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fun yín ní ìṣẹ́gun lórí gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí wọ́n wà ní àyíká yín, ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, pípa ni kí ẹ pa àwọn ará Amaleki run lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé. +bí ó bá jẹ́ pé nínà ni ó yẹ kí wọ́n na ẹni tí ó jẹ̀bi, ẹni náà yóo dọ̀bálẹ̀ níwájú adájọ́, wọn yóo sì nà án ní iye ẹgba tí ó bá tọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. +Ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ nà án ju ogoji ẹgba lọ, ohun ìtìjú ni yóo jẹ́ fún un ní gbangba, bí wọ́n bá nà án jù bẹ́ẹ̀ lọ. +“Ẹ kò gbọdọ̀ dí mààlúù lẹ́nu nígbà tí ẹ bá ń lò ó láti fi pa ọkà. +“Bí àwọn arakunrin meji bá jùmọ̀ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan ninu wọn sì kú láìní ọmọkunrin, aya ẹni tí ó kú kò gbọdọ̀ lọ fẹ́ ará ìta tabi àlejò. Arakunrin ọkọ rẹ̀ ni ó gbọdọ̀ ṣú u lópó, kí ó sì máa ṣe gbogbo ẹ̀tọ́ tí ó bá yẹ fún obinrin náà. +Wọn yóo ka ọmọkunrin kinni tí opó yìí bá bí sí ọmọ ọkọ rẹ̀ tí ó kú, kí orúkọ ọkọ rẹ̀ náà má baà parẹ́ ní Israẹli. +Bí ọkunrin yìí kò bá wá fẹ́ ṣú aya arakunrin rẹ̀ tí ó kú lópó, obinrin náà yóo tọ àwọn àgbààgbà lọ ní ẹnubodè, yóo sì wí pé, ‘Arakunrin ọkọ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arakunrin rẹ̀ ró ní Israẹli, ó kọ̀ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí arakunrin ọkọ mi.’ +Àwọn àgbààgbà ìlú yóo pe ọkunrin náà, wọn óo bá a sọ̀rọ̀, bí ó bá kọ̀ jálẹ̀, tí ó wí pé, ‘Èmi kò fẹ́ fẹ́ ẹ,’ +Lẹ́yìn náà, obinrin náà yóo tọ̀ ọ́ lọ lójú gbogbo àwọn àgbààgbà, yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo tutọ́ sí i lójú, yóo sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ẹni tí ó bá kọ̀ láti kọ́ ilé arakunrin rẹ̀.’ +Ojúṣe Ẹni sí Arakunrin Ẹni Tí Ó Ṣaláìsí. +“Nígbà tí o bá dé orí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ, tí o gbà á, tí o sì ń gbé inú rẹ̀, +Nítorí náà, nisinsinyii, mo mú àkọ́so èso ilẹ̀ tí ìwọ OLUWA ti fi fún mi wá.’“Lẹ́yìn náà, gbé e kalẹ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì sìn ín; +kí o sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ fún ohun tí OLUWA fún ìwọ ati ìdílé rẹ, kí àwọn ọmọ Lefi ati àwọn àlejò tí ń gbé ààrin yín náà sì máa bá ọ ṣe àjọyọ̀. +“Ní ọdún kẹtakẹta, tíí ṣe ọdún ìdámẹ́wàá, tí o bá ti dá ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko rẹ, kí o kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, kí wọ́n lè máa jẹ àjẹyó ninu ìlú yín. +Lẹ́yìn náà, kí o wí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá tíí ṣe ohun ìyàsímímọ́ ni mo ti mú kúrò ninu ilé mi, mo sì ti fi fún àwọn ọmọ Lefi ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo àṣẹ tí o pa fún mi. N kò rú èyíkéyìí ninu àwọn òfin rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì gbàgbé wọn. +N kò jẹ ninu ìdámẹ́wàá mi nígbà tí mò ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò kó èyíkéyìí jáde kúrò ninu ilé mi nígbà tí mo jẹ́ aláìmọ́, tabi kí n fi èyíkéyìí ninu wọn bọ òkú ọ̀run. Gbogbo ohun tí o wí ni mo ti ṣe, OLUWA Ọlọrun mi, mo sì ti pa gbogbo àṣẹ rẹ mọ́. +Bojúwo ilẹ̀ láti ibùgbé mímọ́ rẹ lọ́run, kí o sì bukun Israẹli, àwọn eniyan rẹ, ati ilẹ̀ tí o ti fi fún wa gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún àwọn baba wa, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.’ +“OLUWA Ọlọrun rẹ pàṣẹ fún ọ lónìí, pé kí o máa pa gbogbo ìlànà ati òfin wọnyi mọ́. Nítorí náà, máa pa gbogbo wọn mọ́ tọkàntọkàn. +O ti fi ẹnu ara rẹ sọ lónìí pé, OLUWA ni Ọlọrun rẹ, ati pé o óo máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, o óo máa pa gbogbo ìlànà ati òfin ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, o óo sì máa gbọ́ tirẹ̀. +OLUWA pàápàá sì ti sọ lónìí pé, eniyan òun ni ọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún ọ, ati pé kí o pa gbogbo òfin òun mọ́. +Ó ní òun óo gbé ọ ga ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó dá lọ. O óo níyì jù wọ́n lọ; o óo ní òkìkí jù wọ́n lọ, o óo sì lọ́lá jù wọ́n lọ. O óo jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.” +mú ninu àkọ́so èso ilẹ̀ náà sinu agbọ̀n kan, kí o sì gbé e lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun rẹ yóo yàn pé kí ẹ ti máa sin òun. +Tọ alufaa tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò náà lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Mò ń wí fún OLUWA Ọlọrun mi lónìí pé, mo ti dé ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba wa láti fún wa.’ +“Alufaa yóo gba agbọ̀n èso náà ní ọwọ́ rẹ, yóo sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ. +Lẹ́yìn náà, o óo wí báyìí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Ará Aramea, alárìnká, ni baba ńlá mi, ó lọ sí ilẹ̀ Ijipti, ó sì jẹ́ àlejò níbẹ̀. Wọn kò pọ̀ rárá tẹ́lẹ̀, ṣugbọn níbẹ̀ ni wọ́n ti di pupọ, wọ́n sì di orílẹ̀-èdè ńlá, tí ó lágbára, tí ó sì lókìkí. +Àwọn ará Ijipti lò wá ní ìlò ìkà, wọ́n pọ́n wa lójú, wọ́n sì mú wa sìn bí ẹrú. +A bá kígbe pe OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa; ó gbọ́ ohùn wa, ó rí ìpọ́njú, ati ìṣẹ́, ati ìjìyà wa. +OLUWA fi agbára rẹ̀ kó wa jáde láti Ijipti, pẹlu àwọn iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu. +Ó kó wa wá sí ìhín, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí; ilẹ̀ tí ó ní ọ̀rá tí ó kún fún wàrà ati oyin. +Ọrẹ Ìkórè. +Mose, pẹlu gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli, sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ máa pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́. +Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ máa gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun y��n lẹ́nu, kí ẹ sì máa pa òfin ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, bí èmi Mose ti pàṣẹ fun yín lónìí.” +Mose bá pàṣẹ fún àwọn eniyan náà ní ọjọ́ kan náà, ó ní, +“Nígbà tí ẹ bá kọjá odò Jọdani sí òdìkejì, àwọn ẹ̀yà Simeoni, ẹ̀yà Lefi, ti Juda, ti Isakari, ti Josẹfu ati ti Bẹnjamini yóo dúró lórí òkè Gerisimu láti súre. +Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ti Aṣeri, ti Sebuluni, ti Dani ati ti Nafutali yóo sì dúró lórí òkè Ebali láti búra. +Àwọn ọmọ Lefi yóo wí ketekete fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé: +“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yá ère gbígbẹ́ tabi ère tí wọ́n fi irin rọ. Ohun ìríra ni lójú OLUWA, pé kí àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà fi ọwọ́ gbẹ́ nǹkan, kí ẹnìkan wá gbé e kalẹ̀ níkọ̀kọ̀, kí ó máa bọ ọ́.’ “Gbogbo àwọn eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ +“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá tàbùkù baba tabi ìyá rẹ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ +“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yẹ ààlà ilẹ̀ ẹnìkejì rẹ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ +“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣi afọ́jú lọ́nà.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ +“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹni tí ó bá yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò po, tabi ti aláìní baba, tabi ti opó.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ +Ní ọjọ́ tí ẹ bá kọjá odò Jọdani, tí ẹ bá ti wọ inú ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, ẹ to òkúta ńláńlá jọ kí ẹ fi ohun tí wọ́n fi ń rẹ́ ilé rẹ́ ẹ. +“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, nítorí pé ó dójúti baba rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ +“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹranko lòpọ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo dáhùn pé, ‘Amin.’ +“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀ tabi ọmọ baba rẹ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ +“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ìyá aya rẹ̀ lòpọ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ +“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá pa aládùúgbò rẹ̀ níkọ̀kọ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ +“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa aláìṣẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ +“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí kò bá pa gbogbo àwọn òfin yìí mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’ +Ẹ kọ gbogbo òfin wọnyi sára rẹ̀, nígbà tí ẹ bá ń rékọjá lọ láti wọ ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti ṣèlérí fun yín. +Nígbà tí ẹ bá rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani, ẹ to àwọn òkúta tí mo paláṣẹ fun yín lónìí jọ lórí òkè Ebali, kí ẹ sì fi ohun tí wọ́n fi ń rẹ́ ilé rẹ́ ẹ. +Ẹ fi òkúta kọ́ pẹpẹ kan fún OLUWA níbẹ̀; ẹ kò gbọdọ̀ fi irin gbẹ́ òkúta náà rárá. +Òkúta tí wọn kò gbẹ́ ni kí ẹ fi kọ́ pẹpẹ kan fún OLUWA Ọlọrun yín kí ẹ sì rú ẹbọ sísun sí i lórí rẹ̀. +Ẹ rú ẹbọ alaafia, kí ẹ jẹ ẹ́ níbẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín. +Ẹ kọ gbogbo àwọn òfin wọnyi sára òkúta náà, ẹ kọ wọ́n kí wọ́n hàn ketekete.” +Mose ati àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá wí fún gbogbo ọmọ Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, òní ni ẹ di eniyan OLUWA Ọlọrun yín. +Ìlànà nípa Kíkọ Òfin Ọlọrun Sára Òkúta. +“Bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ, tí o sì farabalẹ̀ pa gbogbo òfin rẹ̀, tí mo ṣe fún ọ lónìí mọ́, OLUWA Ọlọrun rẹ yóo gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù láyé lọ. +Gbogbo eniyan ayé ni yóo rí i pé orúkọ OLUWA ni wọ́n fi ń pè ọ́, wọn yóo sì máa bẹ̀rù rẹ. +OLUWA óo fún ọ ní ọpọlọpọ ọmọ, ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn. Àwọn igi eléso rẹ yóo máa so jìnwìnnì ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ búra fún àwọn baba rẹ, pé òun yóo fún ọ. +OLUWA yóo fún ọ ní ọpọlọpọ òjò ní àkókò rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra rẹ̀ lójú ọ̀run, yóo sì bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ìwọ ni o óo máa yá ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ní nǹkan, o kò sì ní tọrọ lọ́wọ́ wọn. +OLUWA yóo fi ọ́ ṣe orí, o kò ní di ìrù; òkè ni o óo máa lọ, o kò ní di ẹni ilẹ̀; bí o bá pa òfin OLUWA Ọlọrun rẹ, tí mo pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́, tí o mú gbogbo wọn ṣẹ lẹ́sẹẹsẹ, +tí o kò bá yipada ninu àwọn òfin tí mo ṣe fún ọ lónìí, tí o kò sì sá tọ àwọn oriṣa lọ, láti máa bọ wọ́n. +“Ṣugbọn bí o kò bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ, tí o kò sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, bí mo ti fi lélẹ̀ fún ọ lónìí, gbogbo àwọn ègún wọnyi ni yóo ṣẹ sí orí rẹ tí yóo sì mọ́ ọ. +“Ègún ni fún ọ ní ààrin ìlú, ègún ni fún ọ ní oko. +“Ègún ni fún ọkà rẹ ati oúnjẹ rẹ. +“Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, ati fún èso ilẹ̀ rẹ ati fún àwọn ọmọ mààlúù rẹ ati àwọn ọmọ aguntan rẹ. +“Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé, ègún sì ni fún ọ nígbà tí o bá jáde. +Gbogbo ibukun wọnyi ni yóo mọ́ ọ lórí, tí yóo sì ṣẹ sí ọ lára, bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ. +“Bí o bá ṣe ibi, tí o kọ OLUWA sílẹ̀, ninu gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé, èmi OLUWA yóo da ègún lé ọ lórí, n óo sì mú ìdàrúdàpọ̀ ati wahala bá ọ, títí tí o óo fi parun patapata, láìpẹ́, láìjìnnà. +OLUWA yóo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ọ títí tí yóo fi pa ọ́ run patapata, lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti gbà. +OLUWA yóo fi àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ ṣe ọ́, ati ibà, ìgbóná ati ooru; yóo sì rán ọ̀gbẹlẹ̀, ọ̀dá, ati ìrẹ̀dànù sí ohun ọ̀gbìn rẹ, títí tí o óo fi parun. +Òjò kò ní rọ̀, ilẹ̀ yóo sì le bí àpáta. +Dípò òjò, eruku ni yóo máa dà bò ọ́ láti ojú ọ̀run, títí tí o óo fi parun patapata. +“OLUWA yóo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ ṣẹgun rẹ. Bí o bá jáde sí wọn ní ọ̀nà kan, OLUWA yóo tú ọ ká níwájú wọn. Ọ̀rọ̀ rẹ yóo sì di ìyanu ati ẹ̀rù ní gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. +Òkú rẹ yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko tí ń káàkiri orí ilẹ̀ ayé, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni tí óo lé wọn kúrò. +OLUWA yóo da irú oówo tí ó fi bá àwọn ará Ijipti jà bò ọ́, ati egbò, èkúkú ati ẹ̀yi, tí ẹnikẹ́ni kò ní lè wòsàn. +OLUWA yóo da wèrè, ìfọ́jú, ati ìdàrúdàpọ̀ ọkàn bò ọ́. +O óo máa táràrà lọ́sàn-án gangan bí afọ́jú. Kò ní dára fún ọ ní gbogbo ọ̀nà rẹ. Wọn yóo máa ni ọ́ lára, wọn yóo sì máa jà ọ́ lólè nígbà gbogbo; kò sì ní sí ẹnìkan láti ràn ọ́ lọ́wọ́. +“OLUWA yóo bukun ọ ní ààrin ìlú, yóo sì bukun oko rẹ. +“O óo fẹ́ iyawo sọ́nà, ẹlòmíràn ni yóo máa bá a lòpọ̀. O óo kọ́ ilé, o kò sì ní gbé inú rẹ̀. O óo gbin ọgbà àjàrà, o kò sì ní jẹ ninu èso rẹ̀. +Wọn óo máa pa akọ mààlúù rẹ lójú rẹ, o kò ní fẹnu kàn ninu rẹ̀. Wọn óo fi tipátipá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ lọ lójú rẹ, wọn kò sì ní dá a pada fún ọ mọ́. Àwọn aguntan yín yóo di ti àwọn ọ̀tá yín, kò sì ní sí ẹni tí yóo ràn yín lọ́wọ́. +Àwọn ọmọ yín ọkunrin ati àwọn ọmọ yín obinrin óo di ti ẹni ẹlẹ́ni. Ẹ óo retí wọn títí, ẹ kò ní gbúròó wọn, kò sì ní sí ohunkohun tí ẹ lè ṣe sí i. +Orílẹ̀-èdè tí ẹ kò mọ̀ rí ni yóo jẹ ohun ọ̀gbìn yín ati gbogbo làálàá yín ní àjẹrun. Ìnilára ati ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹ óo máa rí nígbà gbogbo, +tóbẹ́ẹ̀ tí ohun tí ẹ óo máa fi ojú yín rí yóo yà yín ní wèrè. +OLUWA yóo da oówo burúkú bò yín lẹ́sẹ̀ ati lórúnkún, yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní lè wò yín sàn. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín títí dé àtàrí yín kìkì oówo ni yóo jẹ́. +“OLUWA yóo lé ẹ̀yin ati ẹni tí ẹ bá fi jọba yín lọ sí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa tí wọ́n fi igi ati òkúta gbẹ́ níbẹ̀. +Ẹ óo di ẹni ìríra, ẹni àmúpòwe ati ẹni ẹ̀sín, láàrin gbogbo àwọn eniyan, níbi tí OLUWA yóo le yín lọ. +“Ọpọlọpọ èso ni ẹ óo máa gbìn sinu oko yín, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ óo máa rí ká, nítorí eṣú ni yóo máa jẹ wọ́n. +Ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì tọ́jú rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò ní rí èso rẹ̀ ká, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní mu ninu ọtí rẹ̀, nítorí pé àwọn kòkòrò yóo ti jẹ ẹ́. +“Yóo bukun àwọn ọmọ rẹ, ati èso ilẹ̀ rẹ, ati àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ, ati àwọn ọmọ mààlúù rẹ, ati àwọn ọmọ aguntan rẹ. +Gbogbo ilẹ̀ yín yóo kún fún igi olifi, ṣugbọn ẹ kò ní rí òróró fi pa ara, nítorí pé rírẹ̀ ni èso olifi yín yóo máa rẹ̀ dànù. +Ẹ óo bí ọpọlọpọ ọmọkunrin ati ọmọbinrin, ṣugbọn wọn kò ní jẹ́ tiyín, nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kó lẹ́rú lọ. +Gbogbo igi yín ati gbogbo èso ilẹ̀ yín ni yóo di ti àwọn eṣú. +“Àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin yín yóo máa níláárí jù yín lọ, ọwọ́ wọn yóo máa ròkè, ṣugbọn ní tiyín, ẹ óo di ẹni ilẹ̀ patapata. +Ọwọ́ àlejò yín ni ẹ óo ti máa tọrọ nǹkan, àwọn kò sì ní tọrọ ohunkohun lọ́wọ́ yín. Àwọn ni wọn yóo jẹ́ orí fun yín, ẹ̀yin yóo sì jẹ́ ìrù fún wọn. +“Gbogbo ègún wọnyi ni yóo ṣẹ si yín lára, tí yóo sì lẹ̀ mọ́ yín pẹ́kípẹ́kí títí tí ẹ óo fi parun, nítorí pé ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò pa òfin rẹ̀ mọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé àwọn ìlànà tí ó pa láṣẹ fun yín. +Àwọn ègún náà yóo wà lórí yín gẹ́gẹ́ bí àmì ati ohun ìyanu, ati lórí àwọn arọmọdọmọ yín títí lae. +Nítorí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun bukun yín, ẹ kọ̀, ẹ kò sìn ín pẹlu ayọ̀ ati inú dídùn. +Nítorí náà, ní ìhòòhò, pẹlu ebi ati òùngbẹ, ati àìní ni ẹ óo fi máa sin àwọn ọ̀tá tí OLUWA yóo rán si yín, yóo sì la àjàgà irin bọ̀ yín lọ́rùn títí tí yóo fi pa yín run. +OLUWA yóo gbé orílẹ̀-èdè kan, tí ẹ kò gbọ́ èdè wọn, dìde si yín láti òpin ayé; wọn óo yára bí àṣá. +“OLUWA yóo fi ibukun rẹ̀ sí orí ọkà rẹ, ati oúnjẹ rẹ. +Ojú gbogbo wọn óo pọ́n kankan, wọn kò ní ṣàánú ọmọde, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní bọ̀wọ̀ fún àgbà. +Wọn yóo jẹ àwọn ọmọ ẹran yín ati èso ilẹ̀ yín títí tí ẹ óo fi parun patapata. Wọn kò ní ṣẹ́ nǹkankan kù fun yín ninu ọkà yín, ọtí waini yín, ati òróró yín, àwọn ọmọ mààlúù tabi ọmọ aguntan yín; títí tí wọn yóo fi jẹ yín run. +Gbogbo ìlú ńláńlá yín ni wọn óo dó tì, títí tí gbogbo odi gíga tí ẹ gbójúlé, tí ó yí àwọn ìlú ńláńlá yín po, yóo fi wó lulẹ̀, ní gbogbo ilẹ̀ yín. Gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní gbogbo ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín ni wọn yóo dó tì. +“Ojú yóo pọn yín tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, nígbà tí àwọn ọ̀tá yin bá dó tì yín, tí yóo fi jẹ́ pé àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ni ẹ óo máa pa jẹ. +Ọkunrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù jùlọ, tí ó sì jẹ́ afínjú jùlọ ninu àwọn ọkunrin yín, yóo di ahun sí arakunrin rẹ̀, ati sí iyawo rẹ̀ tí ó fẹ́ràn jùlọ, ati sí ọmọ rẹ̀ tí ó kù ú kù, +tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní fún ẹnikẹ́ni jẹ ninu ẹran ara ọmọ rẹ̀ tí ó bá ń jẹ ẹ́; nítorí pé kò sí nǹkankan tí ó kù fún un mọ́, ninu ìnira tí àwọn ọ̀tá yín yóo kó yín sí nígbà tí wọ́n ba dó ti àwọn ìlú yín. +Obinrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù jùlọ, tí ó sì jẹ́ afínjú jùlọ ninu àwọn obinrin yín, tí kò jẹ́ fi ẹsẹ̀ lásán tẹ ilẹ̀ nítorí àwọ̀ rẹ̀ tí ó tutù ati ìwà afínjú rẹ̀, yóo di ahun sí ọkọ tí ó jẹ́ olùfẹ́ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin. +Yóo bímọ tán, yóo sì jẹ ibi ọmọ tí ó jáde lára rẹ̀ ní kọ̀rọ̀, yóo sì tún jẹ ọmọ titun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, nítorí pé kò sí ohun tí ó lè jẹ mọ́, nítorí àwọn ọ̀tá yín tí yóo dó ti àwọn ìlú yín. +“Bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò tẹ̀lé gbogbo òfin tí a kọ sinu ìwé yìí, pé kí ẹ máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó lẹ́rù, tí ó sì lógo, +OLUWA yóo mú ìpọ́njú ńlá bá ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín, ìpọ́njú ńlá ati àìsàn burúkú, tí yóo wà lára yín fún ìgbà pípẹ́. +“Yóo bukun ọ nígbà tí o bá ń wọlé, yóo sì tún bukun ọ nígbà tí o bá ń jáde. +Gbogbo àwọn àrùn burúkú ilẹ̀ Ijipti, tí wọ́n bà yín lẹ́rù, ni OLUWA yóo dà bò yín, tí yóo sì wà lára yín. +Àwọn àìsàn mìíràn ati ìpọ́njú tí wọn kò kọ sinu ìwé òfin yìí ni OLUWA yóo dà bò yín títí tí ẹ óo fi parun. +Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ẹ kò ni kù ju díẹ̀ lọ mọ́, nítorí pé ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín. +Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ dídùn inú OLUWA láti ṣe yín ní rere ati láti sọ yín di pupọ, bákan náà ni yóo jẹ́ dídùn inú rẹ̀ láti ba yín kanlẹ̀ kí ó sì pa yín run. OLUWA yóo le yín kúrò lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà. +OLUWA yóo fọ́n yín káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ayé, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa káàkiri, ati èyí tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati èyí tí wọn fi òkúta ṣe, tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí. +Ara kò ní rọ̀ yín rárá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rí ìdí jókòó. OLUWA yóo mú jìnnìjìnnì ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ba yín, yóo sì mú kí ojú yín di bàìbàì. +Ninu hílàhílo ni ẹ óo máa wà nígbà gbogbo, ninu ẹ̀rù ati ìpayà ni ẹ óo máa wà tọ̀sán-tòru. +Àwọn ohun tí ojú yín yóo máa rí yóo kó ìpayà ati ẹ̀rù ba yín, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ilẹ̀ bá ti ṣú, yóo dàbí kí ilẹ̀ ti mọ́; bí ilẹ̀ bá sì ti tún mọ́, yóo dàbí kí ilẹ̀ ti ṣú. +Ọkọ̀ ojú omi ni OLUWA yóo fi ko yín pada sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí mo ti ṣèlérí pé ẹ kò ní pada sí mọ́ lae. Nígbà tí ẹ bá débẹ̀, ẹ óo fa ara yín kalẹ̀ fún títà gẹ́gẹ́ bí ẹrú, lọkunrin ati lobinrin, ṣugbọn ẹ kò ní rí ẹni rà yín.” +“Yóo bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá tí ó bá dìde sí ọ. Bí wọ́n bá gba ọ̀nà kan dìde sí ọ, yẹ́lẹyẹ̀lẹ ni wọn óo fọ́nká nígbà tí wọn bá ń sálọ fún ọ. +“OLUWA yóo bukun ìkórè inú àká rẹ, ati gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé. OLUWA Ọlọrun rẹ yóo bukun ọ ní ilẹ̀ tí ó fún ọ. +“OLUWA yóo ṣe ọ́ ní eniyan rẹ̀, tí ó yà sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ọ, bí o bá pa òfin rẹ̀ mọ́, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. +Ibukun fún Ìgbọràn. +OLUWA pàṣẹ fún Mose pé kí ó bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu mìíràn ní ilẹ̀ Moabu, yàtọ̀ sí èyí tí ó ti bá wọn dá ní òkè Horebu. +“Gbogbo yín pátá ni ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ati gbogbo àwọn olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olóyè ati àwọn ọkunrin Israẹli. +Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín, àwọn aya yín, ati àwọn àlejò tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ yín; àwọn tí wọn ń wá igi fun yín, ati àwọn tí wọn ń pọnmi fun yín. +Kí gbogbo yín lè bá OLUWA Ọlọrun yín dá majẹmu lónìí, +kí ó lè fi ìdí yín múlẹ̀ bí eniyan rẹ̀, kí ó sì máa jẹ́ Ọlọrun yín; gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, ati bí ó ti búra fún Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu àwọn baba ńlá yín. +‘Kìí ṣe ẹ̀yin nìkan ni mò ń bá dá majẹmu yìí, tí mo sì ń búra fún, +ṣugbọn ati àwọn tí wọn kò sí níhìn-ín lónìí, ati ẹ̀yin alára tí ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ni majẹmu náà wà fún.’ +“Ẹ̀yin náà mọ̀ bí ayé wa ti rí ní ilẹ̀ Ijipti, ati bí a ti la ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a gbà kọjá. +Ẹ sì ti rí àwọn ohun ìríra wọn: àwọn oriṣa wọn tí wọ́n fi igi gbẹ́, èyí tí wọ́n fi òkúta gbẹ́, èyí tí wọ́n fi fadaka ṣe, ati èyí tí wọ́n fi wúrà ṣe. +Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí á má ṣe rí ẹnikẹ́ni ninu yín, kì báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, tabi ìdílé kan, tabi ẹ̀yà kan, tí ọkàn rẹ̀ yóo yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín lónìí, tí yóo sì lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń bọ. Nítorí pé, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo dàbí igi tí ń so èso tí ó korò, tí ó sì ní májèlé ninu. +Kí irú ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ majẹmu má baà dá ara rẹ̀ lọ́kàn le pé ‘Kò séwu, bí mo bá fẹ́ mo lè ṣe orí kunkun kí n sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ ara mi.’ Èyí yóo kó ìparun bá gbogbo yín, ati àwọn tí wọn ń ṣe ibi ati àwọn tí wọn ń ṣe rere. +Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ti rí gbogbo ohun tí OLUWA ṣe sí Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, ní ilẹ̀ Ijipti. +OLUWA kò ní dáríjì olúwarẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ibinu ńlá OLUWA ni yóo bá a. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sinu ìwé yìí yóo ṣẹ sí i lára, OLUWA yóo sì pa orúkọ olúwarẹ̀ rẹ́ kúrò láyé. +OLUWA yóo dojú kọ òun nìkan, láti ṣe é ní ibi láàrin gbogbo ẹ̀yà Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ègún tí ó wà ninu majẹmu, tí a kọ sinu ìwé òfin yìí. +“Nígbà tí àwọn arọmọdọmọ yín tí wọn kò tíì bí, ati àwọn àlejò tí wọ́n bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè bá rí ìpọ́njú, ati àrùn tí OLUWA yóo dà bo ilẹ̀ náà, +tí wọ́n bá rí i tí gbogbo ilẹ̀ náà ti di imí ọjọ́ ati iyọ̀, tí gbogbo rẹ di eérú, tí koríko kankan kò lè hù lórí rẹ̀, bíi ìlú Sodomu ati Gomora, Adima ati Seboimu, tí OLUWA fi ibinu ńlá parẹ́, +gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo máa bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi sọ ilẹ̀ yìí dà báyìí? Kí ló dé tí ibinu ńlá OLUWA fi dé sórí ilẹ̀ yìí?’ +Àwọn eniyan yóo sì máa dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọn kò mú majẹmu OLUWA Ọlọrun ṣẹ, tí ó bá àwọn baba wọn dá nígbà tí ó kó wọn jáde ní ilẹ̀ Ijipti. +Wọ́n ń bọ àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí, tí OLUWA kò sì fi lé wọn lọ́wọ́. +Ìdí nìyí tí inú fi bí OLUWA sí ilẹ̀ yìí, tí ó sì mú gbogbo ègún tí a kọ sinu ìwé yìí ṣẹ lé wọn lórí. +OLUWA sì fi ibinu ńlá ati ìrúnú lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn, ó sì fọ́n wọn dà sórí ilẹ̀ mìíràn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí.’ +“Àwọn nǹkan àṣírí mìíràn wà, tí kò hàn sí eniyan àfi OLUWA Ọlọrun wa nìkan, ṣugbọn àwọn nǹkan tí ó fihàn wá jẹ́ tiwa ati ti àwọn ọmọ wa títí lae, kí á lè máa ṣe àwọn nǹkan tí ó wà ninu ìwé òfin yìí. +Ẹ fi ojú yín rí àwọn ìdààmú ńláńlá tí ó bá wọn, ati àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí OLUWA ṣe. +Ṣugbọn títí di òní yìí, OLUWA kò tíì jẹ́ kí òye ye yín, ojú yín kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni etí yín kò gbọ́ràn. +Odidi ogoji ọdún ni mo fi ko yín la ààrin aṣálẹ̀ kọjá. Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni bàtà kò gbó mọ yín lẹ́sẹ̀. +Ẹ kò jẹ oúnjẹ gidi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mu ọtí waini tabi ọtí líle, kí ẹ lè mọ̀ pé OLUWA ni OLUWA Ọlọrun yín. +Nígbà tí ẹ dé ibí yìí, Sihoni, ọba Heṣiboni ati Ogu, ọba Baṣani gbógun tì wá, ṣugbọn a ṣẹgun wọn. +A gba ilẹ̀ wọn, a sì fi fún ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn. +Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ máa tẹ̀lé majẹmu yìí, kí ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé lè máa yọrí sí rere. +Àdéhùn OLUWA pẹlu Israẹli ní Ilẹ̀ Moabu. +“Lẹ́yìn náà, a gbéra, a doríkọ ọ̀nà Baṣani. Ogu, ọba Baṣani, ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ṣígun wá pàdé wa ní Edirei. +A sì tún gba gbogbo àwọn ìlú wọn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, gbogbo ilẹ̀ Gileadi ati gbogbo ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka ati Edirei, àwọn ìlú tí ó wà ninu ìjọba Ogu, ọba Baṣani.” +(Nítorí pé, Ogu, ọba Baṣani nìkan ni ó kù ninu ìran àwọn Refaimu. Irin ni wọ́n fi ṣe pósí rẹ̀, ó sì wà ní Raba, ní ilẹ̀ àwọn Amoni títí di òní olónìí. Igbọnwọ mẹsan-an ni gígùn pósí náà, ó sì fẹ̀ ní igbọnwọ mẹrin. Igbọnwọ tí ó péye ni wọ́n fi ṣe ìdíwọ̀n pósí náà.) +“Nígbà tí a gba ilẹ̀ náà nígbà náà, àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo fún, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni ati ìdajì agbègbè olókè ti Gileadi, pẹlu gbogbo àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀. +Ìdajì tí ó kù lára ilẹ̀ àwọn ará Gileadi, ati gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Baṣani tíí ṣe ìjọba Ogu, ati gbogbo agbègbè Arigobu, ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Manase.”(Gbogbo ilẹ̀ Baṣani ni wọ́n ń pè ní ilẹ̀ àwọn Refaimu. +Jairi láti inú ẹ̀yà Manase ni ó gba gbogbo agbègbè Arigobu tí à ń pè ní Baṣani, títí dé etí ààlà ilẹ̀ àwọn Geṣuri, ati ti àwọn Maakati. Ó sọ àwọn ìlú náà ní orúkọ ara rẹ̀; ó pè wọ́n ní Hafoti Jairi. Orúkọ náà ni wọ́n ń jẹ́ títí di òní olónìí.) +Makiri, láti inú ẹ̀yà Manase ni mo fún ní ilẹ̀ Gileadi. +Àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo sì fún ní agbègbè Gileadi títí dé àfonífojì Anoni, ààrin gbùngbùn àfonífojì náà ni ààlà ilẹ̀ wọn, títí lọ kan odò Jaboku, tíí ṣe ààlà àwọn ará Amoni; +ati ilẹ̀ Araba títí kan odò Jọdani. Láti Kinereti títí dé Òkun Araba tí wọn ń pè ní Òkun Iyọ̀, ní ẹsẹ̀ òkè Pisiga ní apá ìlà oòrùn. +“Mo pàṣẹ fun yín nígbà náà, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun yín ti fi ilẹ̀ yìí fun yín bíi ohun ìní; gbogbo àwọn akọni ninu àwọn ọkunrin yín yóo kọjá lọ pẹlu ihamọra ogun ṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli, arakunrin yín. +Ṣugbọn àwọn aya yín ati àwọn ọmọ yín kéékèèké ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín (mo mọ̀ pé wọ́n ti di pupọ nisinsinyii) yóo wà ninu àwọn ìlú tí mo ti fun yín +Ṣugbọn OLUWA wí fún mi pé, ‘Má bẹ̀rù rẹ̀, nítorí pé mo ti fi òun ati àwọn eniyan rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́, ohun tí o ṣe sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé Heṣiboni ni kí o ṣe sí òun náà.’ +títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún yín, tí àwọn náà yóo wà lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun wọn ní òdìkejì odò Jọdani. Nígbà náà ni olukuluku yín yóo to pada sórí ilẹ̀ tí mo ti fun yín.’ +“Mo sọ fún Joṣua nígbà náà pé; ‘Ṣé ìwọ náà ti fi ojú ara rẹ rí ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe sí àwọn ọba meji wọnyi? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni OLUWA yóo ṣe sí ìjọba yòókù tí ẹ óo gbà. +Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn rárá, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń jà fun yín.’ +“Mo bẹ OLUWA nígbà náà, mo ní, +‘OLUWA Ọlọrun, o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi títóbi ati agbára rẹ han èmi iranṣẹ rẹ ni; nítorí pé, oriṣa wo ló wà, lọ́run tabi láyé yìí tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu bíi tìrẹ? +Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí n kọjá sí òdìkejì Jọdani kí n sì rí ilẹ̀ dáradára náà, agbègbè olókè dáradára nnì ati Lẹbanoni.’ +“Ṣugbọn OLUWA bínú sí mi nítorí yín, kò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi. OLUWA dá mi lóhùn, ó ní, ‘Ó tó gẹ́ẹ́, má ṣe bá mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ́. +Gun orí òkè Pisiga lọ, gbé ojú sókè, kí o sì wo apá ìwọ̀ oòrùn, ati apá àríwá, ati apá gúsù, ati apá ìlà oòrùn. Ojú ni o óo fi rí i, nítorí pé, o kò ní kọjá odò Jọdani yìí sí òdìkejì. +Ṣugbọn pàṣẹ fún Joṣua, mú un lọ́kàn le, kí o sì kì í láyà; nítorí pé, òun ni yóo ṣiwaju àwọn eniyan wọnyi lọ, tí wọn yóo fi gba ilẹ̀ tí o óo rí.’ +“Nítorí náà a bá dúró sí àfonífojì, ní òdìkejì Betipeori.” +“OLUWA Ọlọrun wa bá fi Ogu, ọba Baṣani, lé wa lọ́wọ́, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. A pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan rẹ̀. +A gba gbogbo àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ nígbà náà, kò sí ìlú kan tí a kò gbà lọ́wọ́ wọn ninu gbogbo àwọn ìlú wọn. Gbogbo ìlú wọn jẹ́ ọgọta, gbogbo agbègbè Arigobu ati ìjọba Ogu ní Baṣani ni a gbà. +Wọ́n mọ odi gíga gíga yípo gbogbo àwọn ìlú ọ̀hún, olukuluku wọ́n sì ní odi tí ó ga ati ẹnubodè pẹlu ọ̀pá ìdábùú, láìka ọpọlọpọ àwọn ìlú kéékèèké tí kò ní odi. +A run gbogbo wọn patapata gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe sí Sihoni, ọba Heṣiboni, tí a run gbogbo àwọn ìlú rẹ̀, ati ọkunrin, ati obinrin, ati ọmọde. +Ṣugbọn a kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati àwọn ohun tí a rí ninu ìlú wọn bí ìkógun. +“A gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ọba Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani nígbà náà. Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti àfonífojì Anoni títí dé òkè Herimoni. +(Herimoni Sirioni ni àwọn ará Sidoni ń pe òkè náà, ṣugbọn àwọn ará Amori ń pè é ní Seniri.) +Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Ogu Ọba. +“Nígbà tí gbogbo àwọn ibukun tabi ègún tí mo gbé kalẹ̀ níwájú yín lónìí bá ṣẹ mọ́ yín lára, tí ẹ bá dé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí, tí ẹ bá ranti anfaani tí ẹ ti sọnù, +bí ẹ bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin yìí, tí ẹ bá sì yipada tọkàntọkàn. +“Nítorí pé òfin tí mo fun yín lónìí kò le jù fun yín, kì í sìí ṣe ohun tí apá yín kò ká. +Kì í ṣe òkè ọ̀run ni ó wà, tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo gun òkè ọ̀run lọ, tí yóo lọ bá wa mú un sọ̀kalẹ̀ wá, kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’ +Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní òdìkejì òkun tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo la òkun kọjá fún wa, tí yóo lọ bá wa mú un wá kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’ +Ṣugbọn nítòsí yín ni ọ̀rọ̀ náà wà, ó wà lẹ́nu yín, ó sì wà ninu ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé ẹ lè ṣe é. +“Wò ó, mo gbé ikú ati ìyè kalẹ̀ níwájú yín lónìí, bákan náà ni mo sì gbé ire ati ibi kalẹ̀. +Tí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́ bí mo ti fun yín lónìí, tí ẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin, ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì máa pọ̀ sí i. OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà tí yóo sì di tiyín. +Ṣugbọn bí ọkàn yín bá yipada, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ kí wọn fà yín lọ bọ àwọn oriṣa, tí ẹ sì ń sìn wọ́n, +mo wí fun yín gbangba lónìí pé, ẹ óo parun. Ẹ kò ní pẹ́ rárá lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gòkè Jọdani lọ gbà, tí yóo sì di tiyín. +Mo fi ilẹ̀ ati ọ̀run ṣe ẹlẹ́rìí níwájú yín lónìí, pé mo fun yín ní anfaani láti yan ikú tabi ìyè, ati láti yan ibukun tabi ègún. Nítorí náà, ẹ yan ìyè kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè wà láàyè. +tí ẹ bá yipada sí OLUWA Ọlọrun yín, ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín; tí ẹ bá tún ń gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ sì ń fi tọkàntọkàn tẹ̀lé gbogbo òfin tí mo ṣe fun yín lónìí, +Ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀, kí ẹ sì máa súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè pẹ́ láyé, kí ẹ sì lè máa gbé orí ilẹ̀ tí OLUWA búra láti fún àwọn baba yín, àní Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu.” +OLUWA Ọlọrun yín yóo dá ibukun yín pada, yóo ṣàánú yín, yóo sì tún ko yín pada láti ààrin àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó fọn yín ká sí. +Ibi yòówù tí OLUWA bá fọn yín ká sí ninu ayé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ òpin ayé, OLUWA yóo wa yín rí, yóo sì ko yín jọ. +OLUWA Ọlọrun yín yóo tún da yín pada sí ilẹ̀ àwọn baba yín, ilẹ̀ náà yóo tún pada di tiyín, OLUWA yóo mú kí ó dára fun yín, yóo mú kí ẹ pọ̀ ju àwọn baba yín lọ. +OLUWA Ọlọrun yín yóo fún ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín ní ẹ̀mí ìgbọràn tí ó fi jẹ́ pé ẹ óo fẹ́ràn rẹ̀ tọkàntọkàn, ẹ óo sì wà láàyè. +OLUWA Ọlọrun yín yóo da àwọn ègún wọnyi sórí àwọn ọ̀tá y��n tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín. +Ẹ óo tún máa gbọ́ ti OLUWA, ẹ óo sì máa pa àwọn òfin rẹ̀ tí mò ń fun yín lónìí mọ́. +OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín lọpọlọpọ, ati àwọn ọmọ yín; àwọn ọmọ mààlúù yín, ati àwọn ohun ọ̀gbìn yín, nítorí inú OLUWA yóo tún dùn láti bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe inú dídùn sí àwọn baba yín, +Ìpadà-bọ̀-sípò ati Ibukun Israẹli. +Mose tún bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀. +Mose bá pàṣẹ fún wọn pé, “Ní ìparí ọdún keje-keje, ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀ fún ọdún ìdásílẹ̀, ní àkókò àjọ̀dún àgọ́, +nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sin OLUWA ní ibi tí ó yàn pé kí wọ́n ti máa sin òun, o gbọdọ̀ máa ka òfin yìí sí etígbọ̀ọ́ gbogbo wọn. +Pe àwọn eniyan náà jọ, ati ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati àgbà, ati onílé ati àlejò, tí ó wà ninu ìlú yín, kí wọ́n lè gbọ́, kí wọ́n sì kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, kí wọ́n sì máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ninu òfin yìí. +Kí àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ̀ ọ́n lè gbọ́ nípa rẹ̀, kí wọ́n sì lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ sí òkè odò Jọdani láti gbà.” +OLUWA Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Àkókò ń tó bọ̀ tí o óo kú, pe Joṣua, kí ẹ̀yin mejeeji wá sinu àgọ́ àjọ kí n lè fi ohun tí yóo ṣe lé e lọ́wọ́.” Mose ati Joṣua bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ. +OLUWA fi ara hàn wọ́n ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu ninu àgọ́ náà. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu náà wà ní ẹ̀bá ẹnu ọ̀nà àgọ́. +OLUWA tún sọ fún Mose pé, “Ọjọ́ àtisùn rẹ kù sí dẹ̀dẹ̀. Àwọn eniyan wọnyi yóo lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn ará ilẹ̀ náà ń bọ. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu tí mo bá wọn dá. +Inú mi yóo ru sí wọn ní ọjọ́ náà, èmi náà óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀, n óo mú ojú mi kúrò lára wọn, n óo sì pa wọ́n run. Oríṣìíríṣìí ibi ati wahala ni yóo bá wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo máa wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ǹjẹ́ nítorí pé kò sí Ọlọrun wa láàrin wa kọ́ ni gbogbo ibi wọnyi fi dé bá wa?’ +Láìṣe àní àní, n óo mú ojú kúrò lára wọn ní ọjọ́ náà, nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, nítorí pé wọ́n ti yipada, wọ́n sì ń bọ oriṣa. +“Nítorí náà, kọ orin yìí sílẹ̀ nisinsinyii kí o sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli, kí orin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí mi lọ́dọ̀ wọn. +Ó ní, “Òní ni mo di ẹni ọgọfa ọdún (120), kò ní ṣeéṣe fún mi mọ́, láti máa fò síhìn-ín sọ́hùn-ún. OLUWA ti wí fún mi pé, n kò ní gun òkè odò Jọdani yìí. +Nítorí pé, nígbà tí mo bá kó wọn wọ ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, tí mo ti búra pé n óo fún àwọn baba wọn; nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí wọ́n yó tán, tí wọ́n sì sanra, wọn óo yipada sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọn óo sì máa bọ wọ́n. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu mi. +Nígbà tí ọpọlọpọ ibi ati wahala bá dé bá wọn, orin yìí ni yóo jẹ́ ẹ̀rí fún wọn (nítorí pé arọmọdọmọ wọn yóo máa kọ ọ́, wọn kò sì ní gbàgbé rẹ̀); nítorí pé mo mọ ète tí wọn ń pa, kí ó tilẹ̀ tó di pé mo mú wọn wọ ilẹ̀ tí mo búra láti fún wọn.” +Mose bá kọ orin yìí ní ọjọ́ náà-gan an, ó sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli. +OLUWA fi iṣẹ́ lé Joṣua ọmọ Nuni lọ́wọ́, ó ní, “Múra gírí kí o sì mú ọkàn gidigidi, nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn ọmọ Israẹli wọ ilẹ̀ tí mo ti búra láti fún wọn. N óo wà pẹlu rẹ.” +Nígbà tí Mose kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé òfin yìí tán patapata, +ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA, +ó ní, “Ẹ fi ìwé òfin yìí sí ẹ̀gbẹ́ àpótí majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, kí ó wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pẹlu yín; +nítorí mo mọ̀ pé ọlọ̀tẹ̀ ati olóríkunkun ni yín; nígbà tí mo wà láàyè pẹlu yín lónìí, ẹ̀ ń ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ìgbà tí mo bá kú tán. +Ẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà ẹ̀yà yín wá sọ́dọ̀ mi, ati gbogbo àwọn olórí ninu yín, kí àwọn náà lè máa gbọ́ bí mo ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ sì pe ọ̀run ati ayé láti ṣe ẹlẹ́rìí wọn. +Nítorí mo mọ̀ dájú pé gẹ́rẹ́ tí mo bá kú tán, ìṣekúṣe ni ẹ óo máa ṣe, ẹ óo sì yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo ti pa láṣẹ fun yín, ibi ni yóo sì ba yín ní ọjọ́ iwájú, nítorí pé ẹ óo ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. Iṣẹ́ ọwọ́ yín yóo sì mú un bínú.” +OLUWA Ọlọrun yín tìkalára rẹ̀ ni yóo ṣiwaju yín lọ, yóo ba yín pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà run, tí ẹ ó fi lè gba ilẹ̀ wọn. Joṣua ni yóo sì jẹ́ olórí, tí yóo máa ṣiwaju yín lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí. +Mose ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin náà patapata sí etígbọ̀ọ́ àpéjọ àwọn ọmọ Israẹli. +Bí OLUWA ti ṣe sí Sihoni ati Ogu, ọba àwọn ará Amori, tí ó pa wọ́n run tàwọn ti ilẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni yóo ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè yìí. +OLUWA yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì ṣe wọ́n bí mo ti pa á láṣẹ fun yín ninu òfin tí mo fun yín. +Ẹ múra gírí, kí ẹ sì mú ọkàn gidigidi. Ẹ má bẹ̀rù rárá, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò yín; nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ. Kò ní já yín kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi yín sílẹ̀.” +Mose bá pe Joṣua, ó sọ fún un níwájú gbogbo àwọn eniyan Israẹli, pé, “Múra gírí, kí o sì mú ọkàn gidigidi nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn eniyan wọnyi lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun ti búra fún àwọn baba wọn pé òun yóo fi fún wọn. Ìwọ ni o óo sì fi lé wọn lọ́wọ́. +OLUWA Ọlọrun tìkalárarẹ̀ ni yóo máa ṣiwaju rẹ lọ, yóo sì máa wà pẹlu rẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí àyà fò ọ́.” +Mose bá kọ òfin yìí sílẹ̀, ó fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli. +Joṣua Gba Ipò Mose. +Ó ní:“Tẹ́tísílẹ̀, ìwọ ọ̀run, mo fẹ́ sọ̀rọ̀;gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ, ìwọ ayé. +“Ninu aṣálẹ̀ ni ó ti rí wọn,níbi tí kò sí igi tabi koríko, àfi kìkì yanrìn.Ó yí wọn ká, ó sì ń tọ́jú wọn,Ó sì dáàbò bò wọ́n bí ẹyin ojú rẹ̀. +Bí ẹyẹ idì tií tú ìtẹ́ rẹ̀ ká,láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ bí à á tíí fò,tíí sì í na apá rẹ̀ láti hán wọntí wọ́n bá fẹ́ já bọ́,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ń ṣe sí Israẹli. +OLUWA nìkan ṣoṣo ni ó ṣáájú àwọn eniyan rẹ̀,láìsí ìrànlọ́wọ́ oriṣa kankan. +“Ó fi wọ́n jọba lórí àwọn òkè ayé,ó sì fún wọn ní èso ilẹ̀ jẹ.Ó pèsè oyin fún wọn láti inú àpáta,ó sì mú kí igi olifi hù fún wọn lórí ilẹ̀ olókùúta. +Wọn rí ọpọlọpọ wàrà lára mààlúù wọn,ati ọ̀pọ̀ omi wàrà lára ewúrẹ́ wọn,ó fún wọn ní ọ̀rá ọ̀dọ́ aguntan ati ti àgbò,ó fún wọn ní mààlúù Baṣani, ati ewúrẹ́,ati ọkà tí ó dára jùlọ,ati ọpọlọpọ ọtí waini. +“Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Jeṣuruni, ẹ yó tán,ẹ wá tàpá sí àṣẹ;ẹ rí jẹ, ẹ rí mu, ẹ sì lókun lára;ẹ wá gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín,ẹ sì ń pẹ̀gàn àpáta ìgbàlà yín! +Wọ́n fi ìbọ̀rìṣà wọn sọ OLUWA di òjòwú;wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú kí ibinu OLUWA wọn ru sókè. +Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí àwọn ẹ̀mí burúkú, Àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí,tí àwọn baba wọn kò sì bọ rí. +Ẹ gbàgbé àpáta ìgbàlà yín,ẹ gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín. +“Nígbà tí OLUWA rí ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe,ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀,nítorí pé, wọ́n mú un bínú. +Kí ẹ̀kọ́ mi kí ó máa rọ̀ bí òjò,àní, bí ọ̀wààrà òjò tíí dẹ ewébẹ̀ lọ́rùn;kí ó sì máa sẹ̀ bí ìrì,bí òjò wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tíí tu koríko lára. +Ó ní, ‘N óo mójú kúrò lára wọn,n óo sì máa wò bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí.Nítorí olóríkunkun ni wọ́n,àwọn alaiṣootọ ọmọ! +Nítorí oriṣa lásánlàsàn, wọn sọ èmi Ọlọrun di òjòwú;wọn sì ti fi àwọn ère wọn mú mi bínú.Nítorí náà, èmi náà óo lo àwọn eniyan lásánlàsànláti mu àwọn náà jowú,n óo sì lo aṣiwèrè orílẹ̀-èdè lásánlàsàn kanláti mú wọn bínú. +Nítorí iná ibinu mi ń jó,yóo sì jó títí dé isà òkú.Yóo jó ayé ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu rẹ̀ ní àjórun,tó fi mọ́ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá. +“ ‘N óo da oríṣìíríṣìí ibi sórí wọn,n óo sì rọ òjò ọfà mi sára wọn. +N óo fi ebi pa wọ́n ní àpakú,iná yóo jó wọn ní àjórun,n óo sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n run.N óo jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú pa wọ́n jẹ,n óo sì jẹ́ kí àwọn ejò olóró bù wọ́n ṣán. +Bí idà tí ń pa àwọn kan lójú pópó,bẹ́ẹ̀ ni ikú yóo di ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀dẹ̀dẹ̀.Bó ti ń pa àwọn ọdọmọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa pa àwọn ọdọmọbinrin,ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ati àwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́,gbogbo wọn ni ikú gbígbóná yóo máa mú lọ. +Ǹ bá wí pé kí n fọ́n wọn káàkiri,kí ẹnikẹ́ni má tilẹ̀ ranti wọn mọ́, +ti àwọn ọ̀tá wọn ni mo rò,nítorí pé, ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn yóo máa w�� kiri.Wọn yóo máa wí pé,“Àwa ni a ṣẹgun wọn,kìí ṣe OLUWA ló ṣe é rárá.” ’ +“Nítorí pé aláìlérò orílẹ̀-èdè ni Israẹli,òye kò sì yé wọn rárá. +Bí ó bá ṣe pé wọ́n gbọ́n ni,tí òye sì yé wọn;wọn ì bá ti mọ̀ bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí. +Nítorí pé n óo polongo orúkọ OLUWA,àwọn eniyan rẹ yóo sì sọ nípa títóbi rẹ̀. +Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ṣe lè lé ẹgbẹrun eniyan?Àní, eniyan meji péré ṣe lè lé ẹgbaarun eniyan sá?Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun aláàbò wọn ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀,tí OLUWA sì ti fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́. +Nítorí pé, àwọn ọ̀tá wọn pàápàá mọ̀ pé,Ọlọrun, aláàbò Israẹli, kì í ṣe ẹgbẹ́ àwọn oriṣa wọn. +Àwọn ọ̀tá wọn ti bàjẹ́ bíi Sodomu ati Gomora,wọ́n dàbí àjàrà tí ń so èso tí ó korò tí ó sì lóró. +Oró ejò ni ọtí wọn,àní oró paramọ́lẹ̀ tíí ṣe ikú pani. +“Èmi OLUWA kò gbàgbé ohun tí àwọn ọ̀tá wọn ṣe,ṣebí gbogbo rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀ lọ́dọ̀ mi? +Èmi OLUWA ni ẹlẹ́san, n óo sì gbẹ̀san, nítorí ọjọ́ ń bọ̀, tí àwọn pàápàá yóo yọ̀ ṣubú.Ọjọ́ ìdààmú wọn kù sí dẹ̀dẹ̀,ọjọ́ ìparun wọn sì ń bọ̀ kíákíá. +Nítorí pé, OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre, yóo sì ṣàánú fún àwọn iranṣẹ rẹ̀,nígbà tí ó bá rí i pé wọn kò lágbára mọ́,ati pé kò sí olùrànlọ́wọ́ fún wọn,tí kò sì ṣẹ́ku ẹnìkan ninu wọn,kì báà ṣe ẹrú tabi òmìnira. +Nígbà náà ni yóo bi wọ́n pé,‘Níbo ni àwọn oriṣa yin wà,ati àpáta tí ẹ fi ṣe ààbò yin? +Ṣebí àwọn ni ẹ fún ní ọ̀rá ẹran ìrúbọ yín,àwọn ni ẹ sì rú ẹbọ ohun mímu yín sí?Kí wọ́n dìde, kí wọ́n ràn yín lọ́wọ́ nisinsinyii,kí wọ́n sì dáàbò bò yín. +“ ‘Ṣé ẹ wá rí i nisinsinyii pé,èmi nìkan ṣoṣo ni Ọlọrun,kò sí ọlọrun mìíràn mọ, lẹ́yìn mi.Mo lè pa eniyan,mo sì lè sọ ọ́ di ààyè.Mo lè ṣá eniyan lọ́gbẹ́,mo sì lè wò ó sàn.Bí mo bá gbá eniyan mú,kò sí ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi. +“Pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ OLUWA, àpáta ààbò yín,gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tọ́.Olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì í ṣe àṣìṣe,ẹ̀tọ́ ní í máa ń ṣe nígbà gbogbo. +Níwọ̀n bí mo ṣe jẹ́ Ọlọrun alààyè,mo fi ara mi búra. +Nígbà tí mo bá pọ́n idà mi,tí ó ń kọ yànrànyànràn,n óo fà á yọ láti fi ṣe ẹ̀tọ́.N óo gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi,n óo sì jẹ àwọn tí wọ́n kórìíra mi níyà. +Ọfà mi yóo tẹnu bọ ẹ̀jẹ̀,yóo sì mu àmuyó.Idà mi yóo sì bẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n lòdì sí mi.N kò ni dá ẹnikẹ́ni sí, ninu àwọn tí wọ́n gbógun tì mí,ati àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́,ati àwọn tí wọ́n dì nígbèkùn,gbogbo wọn ni n óo pa.’ +“Ẹ máa yìn ín ẹ̀yin eniyan OLUWA, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,nítorí pé yóo gbẹ̀san lára àwọn tí wọ́n bá pa àwọn iranṣẹ rẹ̀.Yóo sì jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ níyà,yóo sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀.” +Mose wá, ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí etígbọ̀ọ́ àwọn eniyan náà, òun ati Joṣua ọmọ Nuni. +Nígbà tí Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi tán, +ó ní, “Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ba yín sọ lónìí sọ́kàn, kí ẹ sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ yín, kí wọ́n lè pa gbogbo òfin wọnyi mọ́ lẹ́sẹẹsẹ. +Nítorí pé kìí ṣe nǹkan yẹpẹrẹ ni, òun ni ẹ̀mí yín. Bí ẹ bá pa á mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá Jọdani lọ gbà.” +OLUWA sọ fún Mose ní ọjọ́ náà gan-an pé, +“Lọ sí òkè Abarimu tí ó dojú kọ ìlú Jẹriko, ní ilẹ̀ Moabu. Gun orí òkè Nebo lọ, kí o sì wo gbogbo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn eniyan Israẹli. +Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli ti hu ìwà aiṣododo sí i,ẹ kò sì yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ̀ mọ́,nítorí àbùkù yín;ẹ̀yin ìran ọlọ̀tẹ̀ ati ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí. +Orí òkè Nebo yìí ni o óo kú sí, bí Aaroni arakunrin rẹ ṣe kú lórí òkè Hori. +Nítorí pé, ẹ̀yin mejeeji ni ẹ kò hùwà òtítọ́ sí mi láàrin àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí ẹ wà ní odò Meriba Kadeṣi, ní aṣálẹ̀ Sini. Ẹ tàbùkù mi lójú gbogbo àwọn eniyan, ẹ kò bọ̀wọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ níwájú àwọn eniyan náà. +Nítorí náà, o óo fi ojú rí ilẹ̀ náà, ṣugbọn ẹsẹ̀ rẹ kò ní tẹ ilẹ̀ tí n ó fún àwọn eniyan Israẹli.” +Ṣé irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún OLUWA nìyí,ẹ̀yin ìran òmùgọ̀ ati aláìnírònú ẹ̀dá wọnyi?Ṣebí òun ni baba yín, tí ó da yín,Tí ó da yín tán, tí ó sì fi ìd�� yín múlẹ̀. +“Ẹ ranti ìgbà àtijọ́,ẹ ṣe akiyesi ọpọlọpọ ọdún tí ó ti kọjá.Ẹ bèèrè lọ́wọ́ baba yín, yóo fihàn yín,Ẹ bi àwọn àgbààgbà yín,wọn yóo sì sọ fun yín. +Nígbà tí Ọlọrun ọ̀gá ògo pín ilẹ̀ ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó ṣètò ibi tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóo máa gbé,gẹ́gẹ́ bí ìdílé kọ̀ọ̀kan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. +Nítorí pé ìpín OLUWA ni àwọn eniyan rẹ̀,ó yan àwọn ọmọ Jakọbu ní ohun ìní fún ara rẹ̀. +Ìlànà Ìkẹyìn tí Mose fún Wọn. +Ìre tí Mose eniyan Ọlọrun sú fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú nìyí. Ó ní: +Wọn óo kọ́ ilé Jakọbu ní ìlànà rẹ,wọn óo sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli ní òfin rẹ.Àwọn ni wọn óo máa sun turari níbi ẹbọ rẹ,wọn óo sì máa rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ rẹ. +OLUWA, bukun àwọn ohun ìní wọn,sì jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wọn jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lójú rẹ,Fọ́ egungun itan àwọn ọ̀tá wọn,tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́,kí àwọn tí wọ́n bá kórìíra wọn má sì lè gbérí mọ́.” +Ó súre fún ẹ̀yà Bẹnjamini pé:“Bẹnjamini, ẹ̀yà tí OLUWA fẹ́ràn tí ó sì ń dáàbò bò,OLUWA ń ṣọ́ wọn nígbà gbogbo,ó sì ń gbé ààrin wọn.” +Ó súre fún ẹ̀yà Josẹfu pé:“Kí OLUWA rọ òjò ibukun sórí ilẹ̀ wọn,kí ó sì bu omi rin ín láti abẹ́ ilẹ̀ wá. +Kí OLUWA pèsè ọpọlọpọ èso sórí ilẹ̀ wọn,kí ó sì kún fún àwọn èso tí ó dára jùlọ láti ìgbà dé ìgbà. +Kí àwọn òkè ńláńlá àtijọ́ so ọpọlọpọ èso dáradára,kí ọpọlọpọ èso sì bo àwọn òkè kéékèèké. +Kí ilẹ̀ wọn kún fún oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ó dára,pẹlu ibukun láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ń gbé inú pápá tí ń jó.Kí ó wá sórí Josẹfu,àní, sórí ẹni tó jẹ́ aṣiwaju fún àwọn arakunrin rẹ̀. +Àkọ́bí rẹ̀ lágbára bí akọ mààlúù,Ìwo rẹ̀ sì dàbí ìwo mààlúù tí ó lágbára,tí yóo fi máa ti àwọn orílẹ̀-èdè títí dé òpin ayé.Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹgbẹẹgbaarun àwọn ọmọ Efuraimu,ati ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Manase.” +Ó súre fún Sebuluni ati fún Isakari, ó ní:“Máa yọ̀ bí o ti ń jáde lọ, ìwọ Sebuluni,sì máa yọ̀ ninu ilé rẹ, ìwọ Isakari. +Wọn óo pe àwọn àlejò jọ sórí òkè,wọn óo sì máa rú ẹbọ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níbẹ̀.Nítorí wọn óo máa kó ọrọ̀ jọ láti inú òkun,ati dúkìá tí ó farasin láti inú yanrìn etí òkun.” +OLUWA wá láti orí òkè Sinai,ó yọ gẹ́gẹ́ bí oòrùn láti Edomu,ó ràn sórí àwọn eniyan rẹ̀ láti òkè Parani.Ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹgbaarun àwọn ẹni mímọ́,ó gbé iná tí ń jò lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. +Ìre tí ó sú fún ẹ̀yà Gadi ni pé:“Ibukun ni fún ẹni tí ó bukun ilẹ̀ Gadi,Gadi dàbí kinniun tí ó ba láti fani lápá ya, ati láti géni lórí. +Ibi tí ó dára jùlọ ninu ilẹ̀ náà ni wọ́n mú fún ara wọn,nítorí pé ibẹ̀ ni ìpín olórí ogun wà,ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn eniyan náà,àtòun, àtàwọn eniyan náà sì ń pa àṣẹ OLUWA mọ́,wọn sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo.” +Ó súre fun ẹ̀yà Dani pé:“Dani dàbí ẹgbọ̀rọ̀ kinniun, tí ó fò jáde láti Baṣani.” +Ó súre fún ẹ̀yà Nafutali pé:“OLUWA ti ṣíjú rere wo Nafutali,ó sì ti bukun un lọpọlọpọ,ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti adágún Galili,títí lọ kan gúsù gbọ̀ngbọ̀n.” +Ìre tí ó sú fún ẹ̀yà Aṣeri ni pé:“Ibukun ẹ̀yà Aṣeri ta gbogbo ibukun ẹ̀yà yòókù yọ,àyànfẹ́ ni yóo jẹ́ láàrin àwọn arakunrin rẹ̀,ilẹ̀ rẹ̀ yóo sì kún fún òróró olifi. +Ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn rẹ̀ yóo jẹ́ irin ati idẹ,bí iye ọjọ́ orí rẹ̀ bá ti tó, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóo pọ̀ tó.” +Ẹ̀yin ará Jeṣuruni,kò sí ẹni tí ó dàbí Ọlọrun yín,tí ó gun awọsanma lẹ́ṣin ninu ọlá ńlá rẹ̀,láti wá ràn yín lọ́wọ́. +Ọlọrun ayérayé ni ààbò yín,ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi ń gbé yín ró.Bí ẹ ti ń súnmọ́ wájú,bẹ́ẹ̀ ni ó ń lé àwọn ọ̀tá yín jáde,tí ó sì ní kí ẹ máa pa wọ́n run. +Nítorí náà, Israẹli wà ní alaafia,àwọn ọmọ Jakọbu sì ń gbé láìléwu,ní ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati ọtí waini,tí ìrì sì ń sẹ̀ sórí rẹ̀ láti ọ̀run wá. +Ẹ máa fò fún ayọ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli,ta ló tún dàbí yín,ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí OLUWA tìkalárarẹ̀ gbàlà?OLUWA tìkalárarẹ̀ ni ààbò yín, ati idà yín,òun ní ń dáàbò bò yín, tí ó sì ń fun yín ní ìṣẹ́gun.Àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa wá bẹ̀bẹ̀ fún àánú,ẹ óo sì máa tẹ àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn mọ́lẹ̀. +Ọlọrun fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀,gbogbo àwọn tí a yà sọ́tọ̀ fún un wà lọ́wọ́ rẹ̀,nítorí n��à ni wọ́n ṣe ń tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀,tí wọ́n sì ń gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, +nígbà tí Mose bá fún wa ní òfin,tí ó jẹ́ ohun ìní gbogbo eniyan Israẹli. +Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe di ọba ní Jeṣuruni,nígbà tí gbogbo àwọn olórí péjọ,àní, gbogbo àwọn olórí ninu ẹ̀yà Israẹli. +Mose súre fún ẹ̀yà Reubẹni, ó ní:“Ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ni, kò ní parun,àwọn eniyan rẹ̀ kò ní dínkù.” +Ó súre fún ẹ̀yà Juda pé:“OLUWA, gbọ́ igbe ẹ̀yà Juda,nígbà tí wọ́n bá pè fún ìrànwọ́,sì kó wọn pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wọn.Fi ọwọ́ ara rẹ jà fún wọn,sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ọ̀tá wọn.” +Ó súre fún ẹ̀yà Lefi pé: “OLUWA, fún Lefi, ẹni tíí ṣe olódodo, ní Tumimu ati Urimu rẹ;Lefi, tí o dánwò ní Masa,tí o sì bá jà níbi odò tí ó wà ní Meriba; +àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn kò ka òbí àwọn sí, ju ìwọ OLUWA lọ;wọ́n kọ àwọn arakunrin wọn sílẹ̀,wọ́n sì ṣá àwọn ọmọ wọn tì.Nítorí pé wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ,wọ́n sì ń pa majẹmu rẹ mọ́. +Mose Súre fún Àwọn Ẹ̀yà Israẹli. +Mose gbéra láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ó gun orí òkè Nebo lọ títí dé ṣóńṣó òkè Pisiga, tí ó wà ní òdìkejì Jẹriko. OLUWA sì fi gbogbo ilẹ̀ náà hàn án láti Gileadi lọ, títí dé Dani, +Láti ìgbà náà, kò tíì sí wolii mìíràn ní ilẹ̀ Israẹli tí ó dàbí Mose, ẹni tí Ọlọrun bá sọ̀rọ̀ lojukooju. +Kò sì sí ẹlòmíràn tí OLUWA rán láti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lára Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, ní ilẹ̀ Ijipti. +Bẹ́ẹ̀ ni kò sí wolii mìíràn tí ó ní agbára ńlá tabi tí ó ṣe àwọn ohun tí ó bani lẹ́rù bí Mose ti ṣe lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. +gbogbo ilẹ̀ Nafutali, ilẹ̀ Efuraimu, ilẹ̀ Manase, ati gbogbo ilẹ̀ Juda, títí dé etí òkun ìwọ̀ oòrùn, +ilẹ̀ Nẹgẹbu ni apá gúsù ati gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó wà ní àfonífojì Jẹriko, ìlú tí ó kún fún ọ̀pẹ, títí dé ilẹ̀ Soari. +OLUWA wí fún un pé, “Ilẹ̀ tí mo búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé, n óo fi fún àwọn arọmọdọmọ wọn nìyí, mo jẹ́ kí o rí i, ṣugbọn o kò ní dé ibẹ̀.” +Mose iranṣẹ OLUWA kú ní ilẹ̀ Moabu gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA. +OLUWA sin ín sí àfonífojì ilẹ̀ Moabu tí ó dojú kọ Betipeori, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò mọ ibojì rẹ̀ títí di òní olónìí. +Mose jẹ́ ẹni ọgọfa (120) ọdún nígbà tí ó kú, ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù. +Àwọn ọmọ Israẹli ṣọ̀fọ̀ Mose fún ọgbọ̀n ọjọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, wọ́n sì parí ṣíṣe òkú rẹ̀. +Joṣua ọmọ Nuni kún fún ọgbọ́n nítorí pé Mose ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, nítorí náà àwọn ọmọ Israẹli ń gbọ́ tirẹ̀, wọ́n sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose. +Ikú Mose. +Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ fi ọkàn sí àwọn ìlànà ati òfin tí mò ń kọ yín yìí, kí ẹ máa tẹ̀lé wọn, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ń mu yín lọ, kí ẹ sì lè gbà á. +gẹ́gẹ́ bí ẹ ti dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lẹ́bàá òkè Sinai, tí ó fi sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn eniyan náà jọ sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; kí wọ́n sì kọ́ àwọn ọmọ wọn pẹlu.’ +“Lẹ́yìn náà, ẹ súnmọ́ òkè náà, nígbà tí ó ń jóná, tóbẹ́ẹ̀ tí ahọ́n iná náà fẹ́rẹ̀ kan ojú ọ̀run, tí òkùnkùn ati ìkùukùu bo òkè náà. +Ọlọrun ba yín sọ̀rọ̀ láti inú iná náà wá, ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò rí i. Ohùn rẹ̀ nìkan ni ẹ̀ ń gbọ́. +Ó sọ majẹmu rẹ̀ fun yín, tíí ṣe àwọn òfin mẹ́wàá tí ó pa láṣẹ fun yín láti tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sí orí tabili òkúta meji. +OLUWA pàṣẹ fún mi nígbà náà, láti kọ yín ní ìlànà ati òfin rẹ̀, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà. +“Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò rí ìrísí OLUWA ní ọjọ́ tí ó ba yín sọ̀rọ̀ láàrin iná ní Horebu, +ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀ nípa yíyá ère fún ara yín, irú ère yòówù tí ó lè jẹ́; kì báà ṣe akọ tabi abo, +yálà àwòrán ẹrankokẹ́ranko tí ó wà ní orílẹ̀ ayé, tabi àwòrán ẹyẹkẹ́yẹ tí ń fò lójú ọ̀run, +kì báà ṣe àwòrán ohunkohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, tabi àwòrán ẹjakẹ́ja tí ń bẹ ninu omi. +Ẹ ṣọ́ra nígbà tí ẹ bá gbé ojú yín sókè sí ojú ọ̀run, tí ẹ bá rí oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, ati ogunlọ́gọ̀ àwọn ohun tí ó wà ní ojú ọ̀run, kí ọkàn yín má baà fà sí wọn, kí ẹ sì máa bọ àwọn ohun tí OLUWA Ọlọrun yín fún gbogbo eniyan láyé. +Ẹ kò gbọdọ̀ fi kún òfin tí mo fun yín yìí, ẹ kò sì gbọdọ̀ mú kúrò ninu rẹ̀, kí ẹ lè máa pa òfin OLUWA Ọlọrun yín tí mo fun yín mọ́. +Ọlọrun ti yọ yín kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó dàbí iná ìléru ńlá, ó ko yín jáde láti jẹ́ eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jẹ́ lónìí. +Nítorí tiyín gan-an ni OLUWA ṣe bínú sí mi, tí ó sì fi ibinu búra pé, n kò ní kọjá sí òdìkejì Jọdani, n kò sì ní dé ilẹ̀ dáradára náà, tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín. +Nítorí náà, mo níláti kú ní ìhín yìí, n kò gbọdọ̀ rékọjá sí òdìkejì Jọdani, ṣugbọn ẹ̀yin óo rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, ẹ óo sì gba ilẹ̀ dáradára náà. +Ẹ ṣọ́ra gidigidi, ẹ má gbàgbé majẹmu tí OLUWA Ọlọrun yín ba yín dá, ẹ má sì yá èrekére fún ara yín, ní àwòrán ohunkohun, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín lòdì sí i. +Nítorí iná tí ń jó ni run ni OLUWA Ọlọrun yín, Ọlọrun tíí máa ń jowú sì ni. +“Nígbà tí ẹ bá ní ọmọ, ati àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ ti pẹ́ ní ilẹ̀ náà; bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀, nípa yíyá ère ní àwòrán ohunkohun, ati nípa ṣíṣe ohun tí ó burú níwájú OLUWA, tí ó lè mú un bínú, +ọ̀run ati ayé ń gbọ́ bí mo ti ń sọ yìí, pé ẹ óo parun patapata lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ gbà ní òdìkejì Jọdani. Ẹ kò ní pẹ́ níbẹ̀ rárá, ṣugbọn píparun ni ẹ óo parun. +OLUWA yóo fọn yín káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn tí wọn yóo sì ṣẹ́kù ninu yín kò ní tó nǹkan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí. +Ẹ óo sì máa bọ oriṣa tí a fi igi ati òkúta gbẹ́ níbẹ̀. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni àwọn oriṣa wọnyi; wọn kò lè gbọ́ràn, tabi kí wọn ríran; wọn kò lè jẹun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbóòórùn. +Níbẹ̀ ni ẹ óo ti wá OLUWA Ọlọrun yín tí ẹ óo sì rí i, tí ẹ bá wá a tọkàntọkàn pẹlu gbogbo ẹ̀mí yín. +Ẹ̀yin náà ti fi ojú yín rí ohun tí OLUWA ṣe ní Baali Peori, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín pa gbogbo àwọn tí wọn ń bọ oriṣa Baali tí ó wà ní Peori run kúrò láàrin yín. +Nígbà tí ẹ bá wà ninu ìpọ́njú, tí gbogbo nǹkan wọnyi bá ń ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́jọ́ iwájú, ẹ óo pada sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ óo sì gbọ́ tirẹ̀. +Nítorí pé, aláàánú ni OLUWA Ọlọrun yín, kò ní já yín kulẹ̀, kò ní pa yín run, bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbàgbé majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba ńlá yín dá. +“Ẹ lọ wádìí wò bí ó bá ṣẹlẹ̀ rí kí wọ́n tó bí yín, láti ọjọ́ tí Ọlọrun ti dá eniyan, ẹ wádìí káàkiri jákèjádò gbogbo àgbáyé bóyá irú nǹkan ńlá báyìí ṣẹlẹ̀ rí, tabi wọ́n pa á nítàn rí. +Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kan gbọ́ kí oriṣa kan sọ̀rọ̀ láti ààrin gbùngbùn iná rí, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì tún wà láàyè? +Tabi pé, oriṣa kan ti dìde rí, tí ó gbìdánwò àtifi ipá gba orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹlu àmì rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu, ati ogun, ati agbára ati àwọn nǹkan tí ó bani lẹ́rù, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ojú yín rí i tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe fun yín ní Ijipti? +OLUWA fi èyí hàn yín, kí ẹ lè mọ̀ pé òun ni Ọlọrun, ati pé kò sí Ọlọrun mìíràn àfi òun nìkan. +Ó mú kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, kí ó lè kọ yín; ó sì mú kí ẹ rí iná ńlá rẹ̀ láyé, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láàrin iná náà. +Ìdí tí ó fi ṣe èyí ni pé, ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọmọ ọmọ wọn; ó fi agbára ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ó sì wà pẹlu yín. +Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ kúrò fun yín, kí ó baà lè ko yín wọlé kí ó sì fun yín ní ilẹ̀ wọn, kí ẹ sì jogún rẹ̀ bí ó ti wà lónìí. +Kí ẹ mọ̀ lónìí, kí ó sì da yín lójú pé, OLUWA ni Ọlọrun; kò sí ọlọrun mìíràn mọ́ ní ọ̀run ati ní ayé. +Ṣugbọn gbogbo ẹ̀yin tí ẹ di OLUWA Ọlọrun yín mú ṣinṣin ni ẹ wà láàyè títí di òní. +Nítorí náà, ẹ máa pa àwọn ìlànà ati òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ó lè dára fun yín, ati fún àwọn ọmọ yín; kí ẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, títí lae.” +Mose ya ìlú mẹta sọ́tọ̀ ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, gẹ́gẹ́ bí ìlú ààbò, +kí ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan lè máa sálọ sibẹ; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀, láìjẹ́ pé wọ́n ní ìkùnsínú sí ara wọn tẹ́lẹ̀, lè sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi, kí ó lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. +Ó ya Beseri sọ́tọ̀ fún ẹ̀yà Reubẹni ninu aṣálẹ̀ láàrin ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Ó ya Ramoti sọ́tọ̀ ní Gileadi, fún ẹ̀yà Gadi, ó sì ya Golani sọ́tọ̀ ní Baṣani, fún ẹ̀yà Manase. +Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní àwọn òfin; +ó sì fi àwọn ìlànà ati àṣẹ lélẹ̀ fún wọn nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti, +nígbà tí wọ́n dé òdìkejì odò Jọdani, ní àfonífojì tí ó dojú kọ Betipeori, ní ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni. Mose ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun Sihoni nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti. +Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀ ati ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani, Sihoni ati Ogu ni ọba àwọn ará Amori tí wọn ń gbé òdìkejì odò Jọdani ní apá ìlà oòrùn +láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni títí dé òkè Sirioni (tí à ń pè ní òkè Herimoni), +ati gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani títí dé Òkun Araba, tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀, tí ó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Pisiga. +“Mo ti kọ yín ní ìlànà ati òfin gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún mi, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà. +Ẹ máa pa wọ́n mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn, wọn yóo sì sọ yín di ọlọ́gbọ́n ati olóye lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Orílẹ̀-èdè tí ó bá gbọ́ nípa àwọn ìlànà ati òfin wọnyi yóo wí pé, dájúdájú ọlọ́gbọ́n ati amòye eniyan ni yín. +“Ǹjẹ́, orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó tún wà, tí ó ní oriṣa tí ó súnmọ́ ọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun tií súnmọ́ wa nígbàkúùgbà tí a bá pè é? +Tabi orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó tún wà, tí ó ní ìlànà ati òfin òdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn tí mo gbé ka iwájú yín lónìí? +Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ má baà gbàgbé àwọn ohun tí ẹ ti fi ojú ara yín rí, kí iyè yín má baà fò wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ẹ máa pa á nítàn fún àwọn ọmọ yín ati àwọn ọmọ ọmọ yín, +Mose Rọ Àwọn Ọmọ Israẹli Pé kí Wọn Máa Gbọ́ràn. +Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbọ́ àwọn ìlànà ati àwọn òfin tí n óo kà fun yín lónìí; ẹ kọ́ wọn, kí ẹ sì rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀lé wọn. +Ṣugbọn èmi a máa fi ìfẹ́ mi, tí kì í yẹ̀, hàn sí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé òfin mi. +“ ‘O kò gbọdọ̀ pe orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ lásán; nítorí pé, èmi OLUWA yóo dá ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ mi lásán lẹ́bi. +“ ‘Ya ọjọ́ ìsinmi sọ́tọ̀, kí o sì ṣe é ní ọjọ́ mímọ́, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun rẹ ti pàṣẹ fún ọ. +Ọjọ́ mẹfa ni kí o fi ṣe gbogbo làálàá ati iṣẹ́ rẹ; +ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi fún OLUWA Ọlọrun rẹ. Ní ọjọ́ náà, o kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati àwọn ọmọ rẹ obinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ, ati mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, ati àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ, ati àlejò tí ń gbé ilẹ̀ rẹ; kí iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin rẹ lè sinmi bí ìwọ náà ti sinmi. +Ranti pé, ìwọ pàápàá ti jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti rí, ati pé OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó fi agbára rẹ̀ mú ọ jáde. Nítorí náà ni OLUWA Ọlọrun rẹ fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ọjọ́ ìsinmi sọ́tọ̀. +“ ‘Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun rẹ ti pa á láṣẹ fún ọ; kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ, kí ó sì lè máa dára fún ọ. +“ ‘O kò gbọdọ̀ paniyan. +“ ‘O kò gbọdọ̀ ṣe panṣaga. +“ ‘O kò gbọdọ̀ jalè. +OLUWA Ọlọrun wa bá wa dá majẹmu kan ní òkè Horebu. +“ ‘O kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí aládùúgbò rẹ. +“ ‘O kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí aya ẹlòmíràn, tabi ilé rẹ̀, tabi oko rẹ̀, tabi iranṣẹkunrin rẹ̀, tabi iranṣẹbinrin rẹ̀, tabi akọ mààlúù rẹ̀, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tabi ohunkohun tíí ṣe ti ẹlòmíràn.’ +“Àwọn òfin tí OLUWA fún gbogbo yín nìyí, nígbà tí ẹ fi péjọ lẹ́sẹ̀ òkè, tí ó fi fi ohùn rara ba yín sọ̀rọ̀ láti inú iná ati ìkùukùu, ati òkùnkùn biribiri. Àwọn òfin yìí nìkan ni ó fun yín, kò sí òmíràn lẹ́yìn wọn, ó kọ wọ́n sára tabili òkúta meji, ó sì kó wọn fún mi. +“Nígbà tí ẹ gbọ́ ohùn láti inú òkùnkùn biribiri, tí iná sì ń jó lórí òkè, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà yín ati àwọn àgbààgbà wá sọ́dọ̀ mi; +wọ́n ní, ‘OLUWA Ọlọrun wa ti fi títóbi ati ògo rẹ̀ hàn wá, a sì ti gbọ́ ohùn rẹ̀ láàrin iná. Lónìí ni a rí i tí Ọlọrun bá eniyan sọ̀rọ̀, tí olúwarẹ̀ sì tún wà láàyè. +Nítorí náà, kí ló dé tí a óo fi kú? Nítorí pé, iná ńlá yìí yóo jó wa run; bí a bá tún gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa sí i, a óo kú. +Nítorí pé ninu gbogbo ẹ̀dá alààyè, ta ni ó tíì gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun alààyè rí láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́ ọ yìí, tí ó sì wà láàyè? +Ìwọ Mose, súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yóo sọ, kí o wá sọ fún wa, a óo sì ṣe é.’ +“OLUWA gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ̀ ń bá mi sọ̀rọ̀, ó sì wí fún mi pé, ‘Mo gbọ́ ohun tí àwọn eniyan wọnyi bá ọ sọ; gbogbo ohun tí wọ́n sọ pátá ni ó dára. +Yóo ti dára tó, bí wọ́n bá ní irú ẹ̀mí yìí nígbà gbogbo, kí wọ́n bẹ̀rù mi, kí wọ́n sì pa gbogbo òfin mi mọ́, kí ó lè dára fún wọn, ati fún àwọn ọmọ wọn títí lae. +Kì í ṣe àwọn baba wa ni OLUWA bá dá majẹmu yìí, ṣugbọn àwa gan-an tí a wà láàyè níhìn-ín lónìí ni ó bá dá majẹmu náà. +Lọ sọ fún wọn pé, kí wọ́n pada sinu àgọ́ wọn. +Ṣugbọn ìwọ dúró tì mí níhìn-ín, n óo sì sọ gbogbo òfin ati ìlànà ati ìdájọ́ tí o óo kọ́ wọn, kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́, ní ilẹ̀ tí n óo fún wọn.’ +“Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fun yín; ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìgbọràn ninu ohunkohun. +Gbogbo ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín là sílẹ̀ ni kí ẹ máa tọ̀, kí ẹ lè wà láàyè, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ óo gbà. +OLUWA bá yín sọ̀rọ̀ lojukooju lórí òkè ní ààrin iná. +Èmi ni mo dúró láàrin ẹ̀yin ati OLUWA nígbà náà, tí mo sì sọ ohun tí OLUWA wí fun yín; nítorí ẹ̀rù iná náà ń bà yín, ẹ kò sì gun òkè náà lọ.“OLUWA ní, +‘Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ní oko ẹrú tí ẹ wà: +“ ‘O kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, èmi OLUWA ni kí o máa sìn. +“ ‘O kò gbọdọ̀ yá èrekére kankan fún ara rẹ, kì báà jẹ́ ní àwòrán ohunkohun tí ó wà ní ojú ọ̀run tabi ti ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, tabi èyí tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀. +O kò gbọdọ̀ tẹríba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, nítorí pé Ọlọrun tíí máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ìran kẹrin ninu àwọn tí wọ́n kórìíra mi. +Òfin Mẹ́wàá. +“Àwọn òfin ati ìlànà, ati ìdájọ́ tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fún mi láti fi kọ yín nìwọ̀nyí; kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà; +“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mu yín wọ ilẹ̀ tí ó búra fún Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba yín, pé òun yóo fun yín, ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńláńlá tí wọ́n dára, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ tẹ̀ wọ́n dó, +ati àwọn ilé tí ó kún fún àwọn nǹkan dáradára, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ kó wọn sibẹ, ati kànga omi, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbẹ́ ẹ, ati àwọn ọgbà àjàrà ati igi olifi tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbìn ín. Nígbà tí ẹ bá jẹ, tí ẹ yó tán, +ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà gbàgbé OLUWA tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti jẹ́ ẹrú. +Ẹ gbọdọ̀ bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa sìn ín. Orúkọ rẹ̀ ni kí ẹ máa fi búra. +Ẹ kò gbọdọ̀ bọ èyíkéyìí ninu àwọn oriṣa tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín ń bọ, +nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọrun tíí máa ń jowú ni; kí inú má baà bí OLUWA Ọlọrun yín sí yín, kí ó sì pa yín run kúrò lórí ilẹ̀ ayé. +“Ẹ kò gbọdọ̀ dán OLUWA Ọlọrun yín wò, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Masa. +Ẹ gbọdọ̀ pa àwọn òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́ dáradára, kí ẹ sì máa tẹ̀lé àwọn òfin ati àwọn ìlànà rẹ̀, tí ó fi lélẹ̀ fun yín. +Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó tọ́, ati ohun tí ó yẹ lójú OLUWA; kí ó lè dára fun yín, kí ẹ lè lọ gba ilẹ̀ dáradára tí OLUWA ti búra láti fún àwọn baba yín, +kí OLUWA lè lé àwọn ọ̀tá yín jáde fun yín, bí ó ti ṣèlérí. +kí ẹ lè máa bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín, kí ẹ lè máa tẹ̀lé àwọn ìlànà ati òfin tí mo fun yín lónìí, ní gbogbo ọjọ́ ayé yín, kí ẹ lè pẹ́ láyé. +“Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́jọ́ iwájú pé, kí ni ìtumọ̀ àwọn ẹ̀rí ati ìlànà ati òfin tí OLUWA pa láṣẹ fun yín. +Ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘A ti jẹ́ ẹrú Farao ní ilẹ̀ Ijipti rí, ṣugbọn agbára ni OLUWA fi kó wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. +Àwa pàápàá fi ojú wa rí i bí OLUWA ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí wọ́n bani lẹ́rù sí àwọn ará Ijipti ati sí Farao ọba wọn, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀. +OLUWA sì kó wa jáde, kí ó lè kó wa wá sí orí ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba wa. +OLUWA pa á láṣẹ fún wa pé kí á máa tẹ̀lé gbogbo àwọn ìlànà wọnyi, kí á bẹ̀rù òun OLUWA Ọlọrun wa fún ire ara wa nígbà gbogbo, kí ó lè dá wa sí, kí á sì wà láàyè bí a ti wà lónìí yìí. +A óo kà wá sí olódodo bí a bá pa gbogbo àwọn òfin wọnyi mọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun wa, bí ó ti pa á láṣẹ fún wa.’ +Ẹ gbọ́ nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ máa tẹ̀lé àwọn òfin náà, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pọ̀ sí i, ní ilẹ̀ tí ó dára, tí ó kún fún wàrà ati oyin, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti ṣe ìlérí fun yín. +“Ẹ gbọ́ Israẹli: OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA kan ṣoṣo ni. +Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín pẹlu gbogbo ọkàn yín, ati gbogbo ẹ̀mí yín, ati gbogbo agbára yín. +Ẹ fi àṣẹ tí mo pa fun yín lónìí sọ́kàn, +kí ẹ sì fi kọ́ àwọn ọmọ yín dáradára. Ẹ máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ẹ bá jókòó ninu ilé yín, ati nígbà tí ẹ bá ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ati nígbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀, ati nígbà tí ẹ bá dìde. +Ẹ so wọ́n mọ́ ọwọ́ yín gẹ́gẹ́ bí àmì, kí ẹ fi ṣe ọ̀já ìgbàjú, kí ó wà ní agbede meji ojú yín. +Ẹ kọ wọ́n sí ara òpó ìlẹ̀kùn ilé yín, ati sí ara ẹnu ọ̀nà ìta ilé yín. +Òfin Ńlá. +“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá ko yín wọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ yìí, tí ẹ bá gba ilẹ̀ náà, tí OLUWA sì lé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè jáde fun yín, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Hiti, Girigaṣi, Amori, Kenaani, Perisi, Hifi, Jebusi, àní àwọn orílẹ̀-èdè meje tí wọ́n tóbi jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ; +a sì máa san ẹ̀san lojukooju fún àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀. Yóo pa wọ́n run, kò ní dáwọ́ dúró láti má gba ẹ̀san lára gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀, yóo san ẹ̀san fún wọn ní ojúkoojú. +Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra kí ẹ sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì tẹ̀lé ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ tí mo fun yín lónìí. +“Bi ẹ bá fetí sí òfin wọnyi, tí ẹ sì pa wọ́n mọ́, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú majẹmu tí ó bá àwọn baba yín dá ṣẹ lórí yín, yóo sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn. +Yóo fẹ́ràn yín, yóo bukun yín, yóo sọ yín di pupọ, yóo bukun àwọn ọmọ yín, ati èso ilẹ̀ yín, ati ọkà yín, ọtí waini yín, ati òróró yín; yóo bukun àwọn mààlúù yín, yóo sì mú kí àwọn ẹran ọ̀sìn yín kéékèèké pọ̀ sí i, ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fún àwọn baba yín. +OLUWA yóo bukun yín ju gbogbo àwọn eniyan yòókù lọ; kò ní sí ọkunrin kan tabi obinrin kan tí yóo yàgàn láàrin yín, tabi láàrin àwọn ẹran ọ̀sìn yín. +OLUWA yóo mú gbogbo àrùn kúrò lọ́dọ̀ yín, kò sì ní fi ẹyọ kan ninu gbogbo àwọn àrùn burúkú ilẹ̀ Ijipti, tí ẹ mọ̀, ba yín jà. Ṣugbọn yóo dà wọ́n bo àwọn tí wọ́n kórìíra yín. +Píparun ni ẹ óo pa gbogbo àwọn eniyan tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi lé yín lọ́wọ́ run, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọdọ̀ bọ àwọn oriṣa wọn, nítorí ohun ìkọsẹ̀ ni wọn yóo jẹ́ fun yín. +“Bí ẹ bá rò ní ọkàn yín pé àwọn eniyan wọnyi pọ̀ jù yín lọ, ati pé báwo ni ẹ ṣe lè lé wọn jáde, +ẹ ranti ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe sí Farao ati gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn. +Ẹ ranti àwọn àrùn burúkú tí ẹ fi ojú ara yín rí, àwọn àmì ati àwọn iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ agbára tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe kí ó tó kó yín jáde. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni OLUWA Ọlọrun yín yóo ṣe sí gbogbo àwọn eniyan tí ẹ̀ ń bẹ̀rù. +nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi wọ́n le yín lọ́wọ́, tí ẹ bá sì ṣẹgun wọn, píparun ni ẹ gbọdọ̀ pa wọ́n run. Ẹ kò gbọdọ̀ bá wọn dá majẹmu, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú fún wọn rárá. +OLUWA Ọlọrun yín yóo rán agbọ́n sí wọn títí tí gbogbo àwọn tí wọ́n bá farapamọ́ fun yín yóo fi parun. +Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín, nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù ni OLUWA Ọlọrun yín tí ó wà láàrin yín. +Díẹ̀díẹ̀ ni Ọlọrun yóo lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí lọ. Kìí ṣe ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ẹ óo pa gbogbo wọn run, kí àwọn ẹranko burúkú má baà pọ̀ ní ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì ju agbára yín lọ. +Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, yóo sì mú kí ìdàrúdàpọ̀ bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin wọn títí tí wọn yóo fi parun. +Yóo fi àwọn ọba wọn lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì pa orúkọ wọn run ní gbogbo ayé, kò ní sí ẹyọ ẹnìkan tí yóo lè dojú kọ yín títí tí ẹ óo fi pa wọ́n run. +Sísun ni kí ẹ sun gbogbo àwọn ère oriṣa wọn; ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò wúrà tabi fadaka tí ó wà lára wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ kó wọn fún ara yín, kí wọn má baà di ohun ìkọsẹ̀ fun yín, nítorí ohun ìríra ni wọ́n lójú OLUWA Ọlọrun yín. +Ẹ kò sì gbọdọ̀ mú ohun ìríra wọ ilé yín, kí ẹ má baà di ẹni ìfibú gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ohun ìfibú. Ẹ níláti kórìíra wọn, kí ẹ sì yàgò fún wọn, nítorí ohun ìfibú ni wọ́n. +Ẹ kò gbọdọ̀ fi ọmọ yín fún àwọn ọmọkunrin wọn láti fẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ ọmọ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín. +Nítorí pé, wọn óo yí àwọn ọmọ yín lọ́kàn pada, wọn kò ní jẹ́ kí wọ́n tẹ̀lé èmi OLUWA mọ́. Àwọn oriṣa ni wọn óo máa bọ, èmi OLUWA yóo bínú si yín nígbà náà, n óo sì pa yín run kíákíá. +Ohun tí ẹ óo ṣe sí wọn nìyí: ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ rún àwọn òpó wọn, ẹ gé àwọn oriṣa Aṣera wọn lulẹ̀, kí ẹ sì sun gbogbo àwọn ère wọn níná. +Nítorí pé, ẹni mímọ́ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA Ọlọrun yín ti yàn yín, láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní gbogbo ayé, pé kí ẹ jẹ́ ohun ìní fún òun. +“Kì í ṣe pé ẹ pọ̀ ju àwọn eniyan yòókù lọ ni OLUWA fi fẹ́ràn yín, tí ó sì fi yàn yín. Ninu gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yin ni ẹ kéré jùlọ. +Ṣugbọn, nítorí pé OLUWA fẹ́ràn yín, ati nítorí ìbúra tí ó ti ṣe fún àwọn baba yín, ni ó ṣe fi agbára ko yín jáde, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú, lọ́wọ́ Farao, ọba Ijipti. +Nítorí náà, ẹ máa ranti pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun, Ọlọrun olótìítọ́ tíí pa majẹmu mọ́, tíí sì ń fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn sí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, títí dé ẹgbẹrun ìran, +Àwọn Eniyan OLUWA. +“Ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè máa bí sí i, kí ẹ sì lè lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA ti búra láti fún àwọn baba yín. +Nígbà tí ẹ bá jẹun, tí ẹ yó, ẹ óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun yín fún ilẹ̀ dáradára tí ó fun yín. +“Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, nípa àìpa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, ati ìdájọ́ rẹ̀ tí mo fun yín lónìí, +kí ó má jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun, tí ẹ yó tán, tí ẹ ti kọ́ àwọn ilé dáradára, tí ẹ sì ń gbé inú wọn, +nígbà tí agbo mààlúù yín ati agbo aguntan yín bá pọ̀ sí i, tí wúrà ati fadaka yín náà sì pọ̀ sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní bá pọ̀ sí i, +kí ìgbéraga má gba ọkàn yín, kí ẹ sì gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti ń ṣe ẹrú. +Ẹni tí ó mú yín la aṣálẹ̀ ńlá tí ó bani lẹ́rù já, aṣálẹ̀ tí ó kún fún ejò olóró ati àkeekèé, tí ilẹ̀ rẹ̀ gbẹ, tí kò sì sí omi, OLUWA tí ó mú omi jáde fun yín láti inú akọ òkúta, +ẹni tí ó fi mana tí àwọn baba yín kò jẹ rí bọ́ yín ninu aṣálẹ̀, kí ó lè tẹ orí yín ba, kí ó sì dán yín wò láti ṣe yín ní rere níkẹyìn. +Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà sọ ninu ọkàn yín pé agbára yín, ati ipá yín ni ó mú ọrọ̀ yìí wá fun yín. +Ẹ ranti OLUWA Ọlọrun yín nítorí òun ni ó fun yín ní agbára láti di ọlọ́rọ̀, kí ó lè fìdí majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba yín dá múlẹ̀, bí ó ti rí lónìí. +Ṣugbọn, mò ń kìlọ̀ fun yín dáradára lónìí pé, bí ẹ bá gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ̀ ń sá káàkiri tọ àwọn oriṣa lẹ́yìn, tí ẹ sì ń bọ wọ́n, píparun ni ẹ óo parun. +Ẹ ranti gbogbo ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín ti mú yín tọ̀ ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún yìí wá, láti tẹ orí yín ba; ó dán yín wò láti rí ọkàn yín, bóyá ẹ óo pa òfin rẹ̀ mọ́ tabi ẹ kò ní pa á mọ́. +Gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA parun fun yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo parun, nítorí pé ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín. +Ó tẹ orí yín ba, ó jẹ́ kí ebi pa yín, ó fi mana tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí bọ́ yín, kí ẹ lè mọ̀ pé kìí ṣe oúnjẹ nìkan ní o lè mú kí eniyan wà láàyè, àfi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLUWA jáde. +Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ yín kò wú, fún odidi ogoji ọdún yìí. +Nítorí náà, ẹ mọ̀ ninu ara yín pé, gẹ́gẹ́ bí baba ti máa ń bá ọmọ rẹ̀ wí ni OLUWA ń ba yín wí. +Nítorí náà, ẹ pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́, nípa rírìn ní ọ̀nà rẹ̀ ati bíbẹ̀rù rẹ̀. +Nítorí pé ilẹ̀ dáradára ni ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín ń mu yín lọ. Ó kún fún ọpọlọpọ adágún omi, ati orísun omi tí ó ń tú jáde ninu àwọn àfonífojì ati lára àwọn òkè. +Ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati baali, ọgbà àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́, ati igi pomegiranate, ilẹ̀ tí ó kún fún igi olifi ati oyin. +Ilẹ̀ tí ẹ óo ti máa jẹun, tí kò ní sí ọ̀wọ́n oúnjẹ, níbi tí ẹ kò ní ṣe aláìní ohunkohun. Ilẹ̀ tí òkúta rẹ̀ jẹ́ irin, tí ẹ óo sì máa wa idẹ lára àwọn òkè rẹ̀. +Ilẹ̀ Tí Ó Dára fún Ìní. +“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ óo la odò Jọdani kọjá sí òdìkejì lónìí, ẹ óo sì gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, tí odi tí wọ́n mọ yí wọn ká sì ga kan ojú ọ̀run. +OLUWA fún mi ní àwọn tabili òkúta meji náà, tí Ọlọrun fúnrarẹ̀ fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ. Gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ba yín sọ láti ààrin iná, ní ọjọ́ tí ẹ péjọ sí ẹsẹ̀ òkè náà ni ó wà lára àwọn tabili náà. +Lẹ́yìn ogoji ọjọ́, OLUWA kó àwọn tabili òkúta náà, tíí ṣe tabili majẹmu, fún mi. +“OLUWA bá sọ fún mi pé, ‘Dìde, sọ̀kalẹ̀ kíákíá, nítorí pé àwọn eniyan rẹ, tí o kó ti Ijipti wá ti dẹ́ṣẹ̀, wọ́n ti yára yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ti yá ère tí a fi iná yọ́ fún ara wọn.’ +“OLUWA tún sọ fún mi pé, ‘Mo ti rí i pé olórí kunkun ni àwọn eniyan wọnyi. +Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n pa wọ́n run, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò láyé. N óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè tí yóo tóbi, tí yóo sì lágbára jù wọ́n lọ.’ +“Mo bá gbéra, mo sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu àwọn tabili òkúta mejeeji tí a kọ majẹmu náà sí ní ọwọ́ mi. Iná sì ń jó lórí òkè náà. +Ojú tí n óo gbé sókè, mo rí i pé ẹ ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ti yá ère wúrà tí ẹ fi iná yọ́, ẹ ti yára yipada kúrò ní ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fun yín. +Mo bá mú àwọn tabili mejeeji, mo là wọ́n mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn lójú yín. +Mo bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú OLUWA bíi ti àkọ́kọ́, fún ogoji ọjọ́; n kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì mu, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti dá, tí ẹ ṣe ohun tí ó burú níwájú OLUWA, tí ẹ sì mú un bínú. +Nítorí inú tí OLUWA ń bí si yín ati inú rẹ̀ tí kò dùn sí yín bà mí lẹ́rù, nítorí ó ti ṣetán láti pa yín run. Ṣugbọn OLUWA tún gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà náà. +Àwọn eniyan náà pọ̀, wọ́n ṣígbọnlẹ̀. Àwọn òmìrán tíí ṣe ìran Anakimu ni wọ́n. Àwọn tí ẹ ti mọ̀, tí ẹ sì ti ń gbọ́ nípa wọn pé, ‘Ta ni ó lè dúró níwájú àwọn ìran Anaki?’ +Inú bí OLUWA sí Aaroni tóbẹ́ẹ̀ tí OLUWA fi ṣetán láti pa á run, ṣugbọn mo gbadura fún Aaroni nígbà náà. +Mo bá gbé ère ọmọ mààlúù tí ẹ yá, tí ó jẹ́ ohun ẹ̀ṣẹ̀, mo dáná sun ún, mo lọ̀ ọ́ lúbúlúbú, mo sì dà á sinu odò tí ń ṣàn wá láti orí òkè. +“Bẹ́ẹ̀ ni ẹ mú OLUWA bínú ní Tabera ati ní Masa, ati ni Kibiroti Hataafa. +Bákan náà ni ẹ ṣe ní Kadeṣi Banea, nígbà tí OLUWA ran yín lọ, tí ó ní kí ẹ lọ gba ilẹ̀ tí òun ti fi fun yín. Ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbà á gbọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀. +Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín, kò sí ìgbà kan tí ẹ kò ṣe orí kunkun sí OLUWA. +“Mo bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú rẹ̀ fún ogoji ọjọ́ nítorí pé ó pinnu láti pa yín run. +Mo gbadura sí OLUWA, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun, má ṣe pa àwọn eniyan rẹ run. Ohun ìní rẹ ni wọ́n, àwọn tí o ti fi agbára rẹ rà pada, tí o fi ipá kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti. +Ranti Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu, àwọn iranṣẹ rẹ. Má wo ti oríkunkun àwọn eniyan wọnyi, tabi ìwà burúkú wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn,’ +kí àwọn ará ilẹ̀ tí o ti kó wa wá má baà wí pé, ‘OLUWA kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn ati pé ó kórìíra wọn, ni ó ṣe kó wọn wá sinu aṣálẹ̀ láti pa wọ́n. +Nítorí pé, eniyan rẹ ni wọ́n, ohun ìní rẹ ni wọ́n sì jẹ́, àwọn tí o fi agbára ńlá ati ipá kó jáde.’ +Nítorí náà, kí ẹ mọ̀ lónìí pé, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń lọ níwájú yín, bíi iná ajónirun. Yóo pa wọ́n run, yóo sì tẹ orí wọn ba fun yín, nítorí náà, kíá ni ẹ óo lé wọn jáde, tí ẹ óo sì pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín. +“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá lé wọn jáde fun yín, ẹ má ṣe wí ninu ọkàn yín pé, ‘Nítorí òdodo wa ni OLUWA ṣe mú wa wá láti gba ilẹ̀ yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni nítorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ni OLUWA ṣe lé wọn jáde fún wa.’ +Kì í ṣe nítorí ìwà òdodo yín, tabi ìdúróṣinṣin ọkàn yín ni ẹ óo fi rí ilẹ̀ náà gbà; ṣugbọn nítorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín fi ń lé wọn jáde fun yín, kí ó lè mú ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu, àwọn baba yín, ṣẹ. +Nítorí náà, ẹ mọ̀ dájú pé, kì í ṣe nítorí ìwà òdodo yín ni OLUWA Ọlọrun yín fi ń fun yín ní ilẹ̀ dáradára yìí, nítorí pé, olórí kunkun eniyan ni yín. +“Ẹ ranti, ẹ má sì ṣe gbàgbé, bí ẹ ti mú OLUWA Ọlọrun yín bínú ninu aṣálẹ̀, láti ọjọ́ tí ẹ ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti títí tí ẹ fi dé ibí yìí ni ẹ̀ ń ṣe oríkunkun sí OLUWA. +Àní, ní òkè Horebu, ẹ mú kí inú bí OLUWA, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́ pa yín run. +Nígbà tí mo gun orí òkè lọ, láti gba tabili òkúta, tíí ṣe majẹmu tí OLUWA ba yín dá, mo wà ní orí òkè náà fún ogoji ọjọ́, láìjẹ, láìmu. +Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣe Àìgbọràn. +Ọ̀rọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n, ọmọ Dafidi, Ọba Jerusalẹmu nìyí. +Ǹjẹ́ ohun kankan wà tí a lè tọ́ka sí pé: “Wò ó! Ohun titun nìyí.” Ó ti wà rí ní ìgbà àtijọ́. +Kò sí ẹni tí ó ranti àwọn nǹkan àtijọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni, kò sì ní sí ẹni tí yóo ranti àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. +Èmi ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ti jẹ ọba lórí Israẹli, ní Jerusalẹmu. +Mo fi tọkàntọkàn pinnu láti fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ohun tí eniyan ń ṣe láyé.Làálàá lásán ni iṣẹ́ tí Ọlọrun fún ọmọ eniyan ṣe lórí ilẹ̀ ayé. +Mo ti wo gbogbo nǹkan tí eniyan ń ṣe láyé, wò ó, asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀. +Ohun tí ó bá ti wọ́, ẹnìkan kò lè tọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò lè ka ohun tí kò bá sí. +Mo wí lọ́kàn ara mi pé, “Mo ti kọ́ ọpọlọpọ ọgbọ́n, ju gbogbo àwọn tí wọ́n ti jọba ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ. Mo ní ọpọlọpọ ìrírí tí ó kún fún ọgbọ́n ati ìmọ̀.” +Mo pinnu lọ́kàn mi láti mọ ohun tí ọgbọ́n jẹ́, ati láti mọ ohun tí ìwà wèrè ati ìwà òmùgọ̀ jẹ́. Mo wá wòye pé èyí pàápàá jẹ́ ìmúlẹ̀mófo. +Nítorí pé ọpọlọpọ ọgbọ́n a máa mú ọpọlọpọ ìbànújẹ́ wá, ẹni tí ń fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀, ó ń fi kún ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ ni. +Asán ninu asán, bí ọ̀jọ̀gbọ́n ti wí, asán ninu asán, gbogbo rẹ̀ asán ni. +Èrè kí ni eniyan ń jẹ ninu gbogbo làálàá rẹ̀, tí ó ń ṣe nílé ayé? +Ìran kan ń kọjá lọ, òmíràn ń dé, ṣugbọn ayé wà títí laelae. +Oòrùn ń yọ, oòrùn ń wọ̀, ó sì ń yára pada sí ibi tí ó ti yọ wá. +Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúsù, ó sì ń yípo lọ sí ìhà àríwá. Yíyípo ni afẹ́fẹ́ ń yípo, a sì tún pada sí ibi tí ó ti wá. +Inú òkun ni gbogbo odò tí ń ṣàn ń lọ, ṣugbọn òkun kò kún. Ibi tí àwọn odò ti ń ṣàn wá, ibẹ̀ ni wọ́n tún ṣàn pada lọ. +Gbogbo nǹkan ní ń kó àárẹ̀ bá eniyan, ju bí ẹnu ti lè sọ lọ. Ìran kì í sú ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ kì í kún etí. +Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóo máa wà. Ohun tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀ náà ni a óo tún máa ṣe, kò sí ohun titun kan ní ilé ayé. +Asán Ni Ilé Ayé. +Bí òkú eṣinṣin ṣe lè ba òórùn turari jẹ́;bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ kékeré lè ba ọgbọ́n ńlá ati iyì jẹ́. +Ẹni tí kò bá pọ́n àáké rẹ̀ kí ó mú,yóo lo agbára pupọ bí ó bá fẹ́ lò ó,ṣugbọn ọgbọ́n a máa ranni lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí. +Lẹ́yìn tí ejò bá ti buni jẹ tán,kò ṣàǹfààní mọ́ kí á máa pọfọ̀ sí ejò. +Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa bu iyì kún un,ṣugbọn ẹnu òmùgọ̀ ni yóo pa á. +Agọ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀,wèrè sì ni ìparí rẹ̀. +Òmùgọ̀ ń sọ̀rọ̀ láìdákẹ́,kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la,ta ni lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ fún un. +Làálàá ọ̀lẹ ń kó àárẹ̀ bá a,tóbẹ́ẹ̀ tí kò mọ ọ̀nà ìlú mọ́. +Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọde gbé!Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá láàárọ̀. +Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ kì í bá ṣe ọmọ ẹrú ṣoríire!Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá ní àsìkò tí ó tọ́;tí wọn ń jẹ tí wọn ń mu kí wọn lè lágbára,ṣugbọn tí kì í ṣe fún ìmutípara. +Ọ̀lẹ a máa jẹ́ kí ilé ẹni wó,ìmẹ́lẹ́ a máa jẹ́ kí ilé ẹni jò. +Oúnjẹ a máa múni rẹ́rìn-ín,waini a sì máa mú inú ẹni dùn,ṣugbọn owó ni ìdáhùn ohun gbogbo. +Ọkàn ọlọ́gbọ́n eniyan a máa darí rẹ̀ sí ọ̀nà rere,ṣugbọn ọ̀nà burúkú ni ọkàn òmùgọ̀ ń darí rẹ̀ sí. +Má bú ọba, kì báà jẹ́ ninu ọkàn rẹ,má sì gbé ọlọ́rọ̀ ṣépè, kì báà jẹ́ ninu yàrá rẹ,nítorí atẹ́gùn lè gbé ọ̀rọ̀ rẹ lọ,tabi kí àwọn ẹyẹ kan lọ ṣòfófó rẹ. +Ìrìn ẹsẹ̀ òmùgọ̀ láàrin ìgboro ń fihàn pé kò gbọ́n,a sì máa fihan gbogbo eniyan bí ó ti gọ̀ tó. +Bí aláṣẹ bá ń bínú sí ọ,má ṣe torí rẹ̀ kúrò ní ìdí iṣẹ́ rẹ,ìtẹríba lè mú kí wọn dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá tóbi jini. +Nǹkan burúkú tí mo tún rí láyé ni, irú àṣìṣe tí àwọn aláṣẹ pàápàá ń ṣe: +Wọ́n fi àwọn òmùgọ̀ sí ipò gíga, nígbà tí àwọn ọlọ́rọ̀ wà ní ipò tí ó rẹlẹ̀. +Mo rí i tí àwọn ẹrú ń gun ẹṣin, nígbà tí àwọn ọmọ-aládé ń fẹsẹ̀ rìn bí ẹrú. +Ẹni tí ó gbẹ́ kòtò ni yóo jìn sinu rẹ̀,ẹni tí ó bá já ọgbà wọlé ni ejò yóo bùjẹ. +Ẹni tí ó bá ń fọ́ òkúta, ni òkúta í pa lára;ẹni tí ó bá ń la igi, ni igi í ṣe ní jamba. +Gbin nǹkan ọ̀gbìn káàkiri lọpọlọpọ, o óo sì kórè ọpọlọpọ èso nígbà tó bá yá. +Gbé ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn rẹ, má sì gba ìrora láàyè lára rẹ, nítorí asán ni ìgbà èwe ati ìgbà ọmọde. +Gbin àwọn kan síhìn-ín, gbin àwọn kan sọ́hùn-ún, gbìn ín káàkiri oko nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. +Nígbà tí òjò bá ṣú dẹ̀dẹ̀, orí ilẹ̀ ni yóo rọ̀ sí, níbi tí igi bá wó sí, níbẹ̀ náà ni yóo wà. +Ẹni tí ń wo ojú afẹ́fẹ́ kò ní fún irúgbìn kankan,ẹni tí ó bá sì ń wo ṣúṣú òjò kò ní kórè. +Gẹ́gẹ́ bí o kò ti mọ bí ẹ̀mí ṣe ń wọ inú ọmọ ninu aboyún, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ bí Ọlọrun ṣe dá ohun gbogbo. +Fún irúgbìn ní àárọ̀, má sì ṣe dáwọ́ dúró ní ìrọ̀lẹ́, nítorí o kò mọ èyí tí yóo dàgbà, bóyá ti òwúrọ̀ ni tabi ti ìrọ̀lẹ́, tabi àwọn mejeeji. +Ìmọ́lẹ̀ dára, oòrùn sì dùn-ún wò. +Bí eniyan ti wù kí ó pẹ́ láyé tó, kí ó máa yọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, ṣugbọn kí ó ranti pé ọjọ́ tí òun yóo lò ninu ibojì yóo pọ̀ ju èyí tí òun yóo lò láyé lọ. Asán ni ìgbẹ̀yìn gbogbo ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. +Ìwọ ọdọmọkunrin, máa yọ̀ ní ìgbà èwe rẹ, kí inú rẹ máa dùn; máa ṣe bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́, ati bí ó ti tọ́ lójú rẹ. Ṣugbọn ranti pé, Ọlọrun yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ohun tí o bá ṣe. +Nǹkan Tí Ọlọ́gbọ́n Eniyan Ń Ṣe. +Ranti ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ, kí ọjọ́ ibi tó dé, kí ọjọ́ ogbó rẹ tó súnmọ́ etílé, nígbà tí o óo wí pé, “N kò ní inú dídùn ninu wọn.” +Ó wádìí ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára ati ọ̀rọ̀ òdodo, ó sì kọ wọ́n sílẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn. +Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, bẹ́ẹ̀ ni àkójọ òwe tí olùṣọ́-aguntan kan bá sọ dàbí ìṣó tí a kàn tí ó dúró gbọningbọnin. +Ọmọ mi, ṣọ́ra fún ohunkohun tí ó bá kọjá eléyìí, ìwé kíkọ́ kò lópin, àkàjù ìwé a sì máa kó àárẹ̀ bá eniyan. +Kókó gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni ohun tí a ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ pé, bẹ̀rù Ọlọrun, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́, nítorí èyí nìkan ni iṣẹ́ ọmọ eniyan. +Nítorí Ọlọrun yóo mú gbogbo nǹkan tí eniyan bá ṣe wá sí ìdájọ́, ati gbogbo nǹkan àṣírí, ìbáà ṣe rere tabi burúkú. +Kí oòrùn ati ìmọ́lẹ̀ ati òṣùpá ati ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn, kí ìkùukùu tó pada lẹ́yìn òjò; +nígbà tí àwọn tí ń ṣọ́ ilé yóo máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí ẹ̀yìn àwọn alágbára yóo tẹ̀, tí àwọn òòlọ̀ yóo dákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí pé wọn kò pọ̀ mọ́, tí àwọn tí ń wo ìta láti ojú fèrèsé yóo máa ríran bàìbàì; +tí àwọn ìlẹ̀kùn yóo tì ní ìgboro, tí ariwo òòlọ̀ yóo rọlẹ̀, tí ohùn ẹyẹ lásán yóo máa jí eniyan kalẹ̀, tí àwọn ọdọmọbinrin tí wọn ń kọrin yóo dákẹ́; +ẹ̀rù ibi gíga yóo máa bani, ìbẹ̀rù yóo sì wà ní ojú ọ̀nà; tí igi alimọndi yóo tanná, tí tata yóo rọra máa wọ́ ẹsẹ̀ lọ, tí ìfẹ́ ọkàn kò ní sí mọ́, nítorí pé ọkunrin ń lọ sí ilé rẹ̀ ayérayé, àwọn eniyan yóo sì máa ṣọ̀fọ̀ kiri láàrin ìgboro; +kí ẹ̀wọ̀n fadaka tó já, kí àwo wúrà tó fọ́; kí ìkòkò tó fọ́ níbi orísun omi, kí okùn ìfami tó já létí kànga; +kí erùpẹ̀ tó pada sí ilẹ̀ tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀mí tó pada tọ Ọlọrun tí ó fúnni lọ. +Asán ninu asán, ọ̀jọ̀gbọ́n ní, asán ni gbogbo rẹ̀. +Yàtọ̀ sí pé ọ̀jọ̀gbọ́n náà gbọ́n, ó tún kọ́ àwọn eniyan ní ìmọ̀. Ó wádìí àwọn òwe fínnífínní, ó sì tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ. +Kókó Gbogbo Ọ̀rọ̀ náà. +Mo wí ninu ọkàn mi pé, n óo dán ìgbádùn wò; n óo gbádùn ara mi, ṣugbọn, èyí pàápàá, asán ni. +Kò sí ohunkohun tí ojú mi fẹ́ rí tí n kò fún un. Kò sí ìgbádùn kan tí n kò fi tẹ́ ara mi lọ́rùn, nítorí mo jẹ ìgbádùn gbogbo ohun tí mo ṣe. Èrè gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi nìyí. +Lẹ́yìn náà, ni mo ro gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi, ati gbogbo làálàá mi lórí rẹ̀; sibẹ: mo wòye pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀, kò sì sí èrè kankan láyé. +Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa ìwà ọlọ́gbọ́n, ìwà wèrè ati ìwà òmùgọ̀. Mo rò ó pé kí ni ẹnìkan lè ṣe lẹ́yìn èyí tí ọba ti ṣe ṣáájú rẹ̀? +Mo wá rí i pé bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ ni ọgbọ́n dára ju ìwà wèrè lọ. +Ọlọ́gbọ́n ní ojú lágbárí, ṣugbọn ninu òkùnkùn ni òmùgọ̀ ń rìn. Sibẹ mo rí i pé, nǹkankan náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn. +Nígbà náà ni mo sọ lọ́kàn ara mi pé, “Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí òmùgọ̀ ni yóo ṣẹlẹ̀ sí èmi náà. Kí wá ni ìwúlò ọgbọ́n mi?” Mo sọ fún ara mi pé, asán ni eléyìí pẹlu. +Nítorí pé àtọlọ́gbọ́n, àtòmùgọ̀, kò sẹ́ni tíí ranti wọn pẹ́ lọ títí. Nítorí pé ní ọjọ́ iwájú, gbogbo wọn yóo di ẹni ìgbàgbé patapata. Ẹ wo bí ọlọ́gbọ́n ti í kú bí òmùgọ̀. +Nítorí náà mo kórìíra ayé, nítorí gbogbo nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ láyé ń bà mí ninu jẹ́, nítorí pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo wọn. +Mo kórìíra làálàá tí mo ti ṣe láyé, nígbà tí mo rí i pé n óo fi í sílẹ̀ fún ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi. +Ta ni ó sì mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ni yóo jẹ́, tabi òmùgọ̀ eniyan? Sibẹsibẹ òun ni yóo jọ̀gá lórí gbogbo ohun tí mo fi ọgbọ́n mi kó jọ láyé yìí. Asán ni èyí pẹlu. +Mo ní, “Ẹ̀rín rínrín dàbí ìwà wèrè, ìgbádùn kò sì jámọ́ nǹkankan fún eniyan.” +Nítorí náà mo pada kábàámọ̀ lórí gbogbo ohun tí mo fi làálàá kójọ. +Nítorí pé nígbà mìíràn ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹlu ọgbọ́n, ìmọ̀ ati òye yóo fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí kò ṣe làálàá fún wọn. Asán ni èyí pẹlu, nǹkan burúkú sì ni. +Kí ni eniyan rí gbà ninu gbogbo làálàá rẹ̀, kí sì ni èrè eniyan lórí akitiyan, ati iṣẹ́ tí ó ń ṣe láyé. +Nítorí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ kún fún ìrora, iṣẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ ìbànújẹ́ fún un. Ọkàn rẹ̀ kì í balẹ̀ lóru, asán ni èyí pẹlu. +Kò sí ohun tí ó dára fún eniyan ju kí ó jẹun kí ó sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lọ. Sibẹ mo rí i pé ọwọ́ Ọlọrun ni èyí tún ti ń wá. +Nítorí láìsí àṣẹ rẹ̀, ta ló lè jẹun, tabi kí ó gbádùn ohunkohun. +Ọlọrun a máa fún ẹni tí ó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati inú dídùn; ṣugbọn iṣẹ́ àtikójọ ati àtitòjọ níí fún ẹlẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè fún àwọn tí ó bá wu Ọlọrun. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá. +Mo ronú bí mo ti ṣe lè fi waini mú inú ara mi dùn, ṣugbọn tí kò ní pa ọgbọ́n mọ́ mi ninu; mo tún ronú ohun tí mo lè ṣe pẹlu ìwà òmùgọ̀ títí tí n óo fi lè rí ohun tí ó dára fún ọmọ eniyan láti máa ṣe láyé níwọ̀n àkókò díẹ̀ tí Ọlọrun fún wọn láti gbé lórí ilẹ̀ ayé. +Mo gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe: mo kọ́ ilé, mo gbin ọgbà àjàrà fún ara mi. +Mo ní ọpọlọpọ ọgbà ati àgbàlá, mo sì gbin oríṣìíríṣìí igi eléso sinu wọn. +Mo gbẹ́ adágún omi láti máa bomirin àwọn igi tí mo gbìn. +Mo ra ọpọlọpọ ẹrukunrin ati ẹrubinrin, mo sì ní àwọn ọmọ ẹrú tí wọn bí ninu ilé mi, mo ní ọpọlọpọ agbo mààlúù ati agbo ẹran, ju àwọn tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ. +Mo kó fadaka ati wúrà jọ fún ara mi; mo gba ìṣúra àwọn ọba ati ti àwọn agbègbè ìjọba mi. Mo ní àwọn akọrin lọkunrin ati lobinrin, mo sì ní ọpọlọpọ obinrin tíí mú inú ọkunrin dùn. +Nítorí náà, mo di eniyan ńlá, mo ju ẹnikẹ́ni tí ó ti wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ, ọgbọ́n sì tún wà lórí mi. +Gbogbo nǹkan láyé yìí ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀: +Mo ti mọ ẹrù ńlá tí Ọlọrun dì ru ọmọ eniyan. +Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, ní àkókò rẹ̀. Ó fi ayérayé sí ọkàn eniyan, sibẹ, ẹnikẹ́ni kò lè rídìí ohun tí Ọlọrun ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. +Mo mọ̀ pé kò sí ohun tí ó yẹ wọ́n ju pé kí inú wọn máa dùn, kí wọ́n sì máa ṣe rere ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; +ati pé ẹ̀bùn Ọlọrun ni pé kí olukuluku jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lẹ́yìn làálàá rẹ̀. +Mo mọ̀ pé gbogbo ohun tí Ọlọrun ṣe, yóo wà títí lae. Kò sí ohun tí ẹ̀dá lè fi kún un, tabi tí ẹ̀dá lè yọ kúrò níbẹ̀, Ọlọrun ni ó dá a bẹ́ẹ̀ kí eniyan lè máa bẹ̀rù rẹ̀. +Ohunkohun tí ó wà, ó ti wà tẹ́lẹ̀, èyí tí yóo sì tún wà, òun pàápàá ti wà rí; Ọlọrun yóo ṣe ìwádìí gbogbo ohun tí ó ti kọjá. +Mo rí i pé ninu ayé yìí ibi tí ó yẹ kí ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo wà ibẹ̀ gan-an ni ìwà ìkà wà. +Mo wí ní ọkàn ara mi pé, Ọlọrun yóo dájọ́ fún olódodo ati fún eniyan burúkú; nítorí ó ti yan àkókò fún ohun gbogbo ati fún iṣẹ́ gbogbo. +Mo wí ní ọkàn ara mi pé Ọlọrun ń dán àwọn ọmọ eniyan wò, láti fihàn wọ́n pé wọn kò yàtọ̀ sí ẹranko; +nítorí kò sí ìyàtọ̀ láàrin òpin eniyan ati ti ẹranko. Bí eniyan ṣe ń kú, ni ẹranko ṣe ń kú. Èémí kan náà ni wọ́n ń mí; eniyan kò ní anfaani kankan ju ẹranko lọ; nítorí pé asán ni ohun gbogbo. +àkókò bíbí wà, àkókò kíkú sì wà;àkókò gbígbìn wà, àkókò kíkórè ohun tí a gbìn sì wà. +Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ; inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá, inú erùpẹ̀ ni wọn yóo sì pada sí. +Ta ló mọ̀ dájúdájú, pé ẹ̀mí eniyan a máa gòkè lọ sọ́run; tí ti ẹranko sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ sinu ilẹ̀? +Nítorí náà, mo rí i pé kò sí ohun tí ó dára, ju pé kí eniyan jẹ ìgbádùn iṣẹ́ rẹ̀ lọ, nítorí ìpín tirẹ̀ ni. Ta ló lè dá eniyan pada sáyé, kí ó wá rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ó bá ti kú? +Àkókò pípa wà, àkókò wíwòsàn sì wà,àkókò wíwó lulẹ̀ wà, àkókò kíkọ́ sì wà. +Àkókò ẹkún wà, àkókò ẹ̀rín sì wà;àkókò ọ̀fọ̀ wà, àkókò ijó sì wà. +Àkókò fífọ́n òkúta ká wà, àkókò kíkó òkúta jọ sì wà;àkókò ìkónimọ́ra wà, àkókò àìkónimọ́ra sì wà. +Àkókò wíwá nǹkan wà, àkókò sísọ nǹkan nù wà;àkókò fífi nǹkan pamọ́ wà, àkókò dída nǹkan nù sì wà. +Àkókò fífa nǹkan ya wà, àkókò rírán nǹkan pọ̀ sì wà;àkókò dídákẹ́ wà, àkókò ọ̀rọ̀ sísọ sì wà. +Àkókò láti fi ìfẹ́ hàn wà àkókò láti kórìíra sì wà;àkókò ogun wà, àkókò alaafia sì wà. +Kí ni èrè làálàá òṣìṣẹ́? +Ohun Gbogbo ni Ó ní Àkókò Tirẹ̀. +Mo tún rí i bí àwọn eniyan tí ń ni ẹlòmíràn lára láyé.Wò ó! Omi ń bọ́ lójú àwọn tí à ń ni lára,Kò sì sí ẹnìkan tí yóo tù wọ́n ninu.Ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára ni agbára kọ̀dí sí,kò sì sí ẹni tí yóo tu àwọn tí à ń ni lára ninu. +Bí ọ̀kan bá ṣubú,ekeji yóo gbé e dìde.Ṣugbọn ẹni tí ó dá wà gbé!Nítorí nígbà tí ó bá ṣubúkò ní sí ẹni tí yóo gbé e dìde. +Bẹ́ẹ̀ sì tún ni, bí eniyan meji bá sùn pọ̀,wọn yóo fi ooru mú ara wọnṣugbọn báwo ni ẹnìkan ṣe lè fi ooru mú ara rẹ̀? +Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni eniyan kan lè dojú ìjà kọ,nítorí pé eniyan meji lè gba ara wọn kalẹ̀.Okùn onípọn mẹta kò lè ṣe é já bọ̀rọ̀. +Ọlọ́gbọ́n ọdọmọde tí ó jẹ́ talaka, sàn ju òmùgọ̀ àgbàlagbà ọba, tí kò jẹ́ gba ìmọ̀ràn lọ, +kì báà jẹ́ pé láti ọgbà ẹ̀wọ̀n ni òmùgọ̀ ọba náà ti bọ́ sórí ìtẹ́, tabi pé láti inú ìran talaka ni a ti bí i. +Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn kiri láyé ati ọdọmọde náà tí yóo gba ipò ọba. +Àwọn eniyan tí ó jọba lé lórí pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní òǹkà; sibẹ, àwọn ìran tí ó bá dé lẹ́yìn kò ní máa yọ̀ nítorí rẹ̀. Dájúdájú asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí. +Mo wá rò ó pé, àwọn òkú, tí wọ́n ti kú,ṣe oríire ju àwọn alààyè tí wọ́n ṣì wà láàyè lọ. +Ṣugbọn ti ẹni tí wọn kò tíì bí rárá,sàn ju ti àwọn mejeeji lọ,nítorí kò tíì rí iṣẹ́ ibití àwọn ọmọ aráyé ń ṣe. +Mo rí i pé gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe ati gbogbo akitiyan rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ó ń ṣe é nítorí pé eniyan ń jowú aládùúgbò rẹ̀ ni. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá. +Òmùgọ̀ eniyan níí káwọ́ gbera,tíí fi ebi pa ara rẹ̀ dójú ikú. +Ó sàn kí eniyan ní nǹkan díẹ̀ pẹlu ìbàlẹ̀ àyàju pé kí ó ní ọpọlọpọ, pẹlu làálàá ati ìmúlẹ̀mófo lọ. +Mo tún rí ohun asán kan láyé: +Ọkunrin kan wà tí kò ní ẹnìkan,kò lọ́mọ, kò lárá, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyekan,sibẹsibẹ làálàá rẹ̀ kò lópin,bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìtẹ́ló��rùn ninu ọrọ̀ rẹ̀.Kò fijọ́ kan bi ara rẹ̀ léèrè rí pé, “Ta ni mò ń ṣe làálàá yìí fúntí mo sì ń fi ìgbádùn du ara mi?”Asán ni èyí pàápàá ati ìmúlẹ̀mófo. +Eniyan meji sàn ju ẹnìkan ṣoṣo lọ,nítorí wọn yóo lè jọ ṣiṣẹ́,èrè wọn yóo sì pọ̀. +Ṣọ́ra, nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọrun, ó sàn kí o lọ máa kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ ju pé kí o lọ máa rúbọ bí àwọn aṣiwèrè tí ń ṣe, tí wọn kò sì mọ̀ pé nǹkan burúkú ni àwọn ń ṣe. +Kò sí iye tó lè tẹ́ ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó lọ́rùn; bákan náà ni ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọrọ̀, kò sí iye tí ó lè jẹ lérè tí yóo tẹ́ ẹ lọ́rùn. Asán ni èyí pẹlu. +Bí ọrọ̀ bá ti ń pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn tí yóo máa lò ó yóo máa pọ̀ sí i. Kò sì sí èrè tí ọlọ́rọ̀ yìí ní ju pé ó fi ojú rí ọrọ̀ rẹ̀ lọ. +Oorun dídùn ni oorun alágbàṣe, kì báà yó, kì báà má yó; ṣugbọn ìrònú ọrọ̀ kì í jẹ́ kí ọlọ́rọ̀ sùn lóru. +Nǹkankan ń ṣẹlẹ̀, tí ó burú, tí mo ṣàkíyèsí láyé yìí, àwọn eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ fún ìpalára ara wọn. +Àdáwọ́lé wọn lè yí wọn lọ́wọ́, wọ́n sì lè fi bẹ́ẹ̀ pàdánù ọrọ̀ wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè rí nǹkankan fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. +Bí eniyan ti wáyé níhòòhò láìmú nǹkankan lọ́wọ́ wá bẹ́ẹ̀ ni yóo pada, láìmú nǹkankan lọ́wọ́ lọ, bí èrè làálàá tí a ṣe láyé. +Nǹkan burúkú gan-an ni èyí pàápàá jẹ́; pé bí a ṣe wá bẹ́ẹ̀ ni a óo ṣe lọ. Tabi èrè wo ni ó wà ninu pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo làálàá wa láyé. +Ninu òkùnkùn, ati ìbànújẹ́ ni a ti ń lo ìgbésí ayé wa, pẹlu ọpọlọpọ ìyọnu, àìsàn ati ibinu. +Wò ó! Ohun tí mo rí pé ó dára jù, tí ó sì yẹ, ni pé kí eniyan jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn gbogbo làálàá tí ó ń ṣe láyé, ní ìwọ̀nba ọjọ́ tí Ọlọrun fún un, nítorí èyí ni ìpín rẹ̀. +Gbogbo ẹni tí Ọlọrun bá fún ní ọrọ̀ ati ohun ìní, ati agbára láti gbádùn wọn, ati láti gba ìpín rẹ̀ kí ó sì láyọ̀ ninu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ̀bùn Ọlọrun ni. +Má fi ẹnu rẹ sọ ìsọkúsọ, má sì kánjú sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọrun, nítorí Ọlọrun ń bẹ lọ́run ìwọ sì wà láyé, nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ níwọ̀n. +Kò ní ranti iye ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí pé, Ọlọrun ti fi ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀. +Ọpọlọpọ àkóléyà ní ń mú kí eniyan máa lá àlákálàá, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni eniyan sì fi ń mọ òmùgọ̀. +Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Ọlọrun, má fi falẹ̀, tètè san án, nítorí kò ní inú dídùn sí àwọn òmùgọ̀. +Ó sàn kí o má jẹ́ ẹ̀jẹ́ rárá ju pé kí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí o má mú un ṣẹ lọ. +Má jẹ́ kí ẹnu rẹ mú ọ dẹ́ṣẹ̀, kí o má baà lọ máa yí ohùn pada lọ́dọ̀ iranṣẹ Ọlọrun pé, èèṣì ló ṣe. Má jẹ́ kí Ọlọrun bínú sí ọ, kí ó má baà pa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ run. +Nígbà tí àlá bá pọ̀ ọ̀rọ̀ náà yóo pọ̀. Ṣugbọn pataki ni pé, ǹjẹ́ o tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọrun? +Bí o bá wà ní agbègbè tí wọ́n ti ń pọ́n talaka lójú, tí kò sì sí ìdájọ́ òdodo ati ẹ̀tọ́, má jẹ́ kí èyí yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí ẹni tí ó ga ju ọ̀gá àgbà lọ ń ṣọ́ ọ̀gá àgbà. Ẹni tó tún ga ju àwọn náà lọ tún ń ṣọ́ gbogbo wọn. +Ju gbogbo rẹ̀ lọ, anfaani ni ilẹ̀ tí à ń dáko sí jẹ́ fún ọba. +Ronú Wò Kí O tó Ṣèlérí. +Mo tún rí nǹkankan tí ó burú nílé ayé. Ó sì wọ ọmọ eniyan lọ́rùn pupọ. +Ohunkohun tí ó bá ti wà, ó ti ní orúkọ tẹ́lẹ̀, a sì ti mọ ẹ̀dá eniyan, pé eniyan kò lè bá ẹni tí ó lágbára jù ú lọ jà. +Asán a máa pọ̀ ninu ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀; kì í sì í ṣe eniyan ní anfaani. +Ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún eniyan láàrin ìgbà kúkúrú, tí kò ní ìtumọ̀, tí ó níí gbé láyé, àkókò tí ó dàbí òjìji tí ó ń kọjá lọ. Ta ló mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ láyé lẹ́yìn òun, lẹ́yìn tí ó bá ti kú tán? +Ẹni tí Ọlọrun fún ní ọrọ̀, ohun ìní ati iyì, tí ó ní ohun gbogbo tí ó fẹ́; sibẹsibẹ Ọlọrun kò jẹ́ kí ó gbádùn rẹ̀, ṣugbọn àjèjì ni ó ń gbádùn rẹ̀. Asán ni èyí, ìpọ́njú ńlá sì ni. +Bí ẹnìkan bá bí ọgọrun-un ọmọ, tí ó sì gbé ọpọlọpọ ọdún láyé, ṣugbọn tí kò gbádùn àwọn ohun tí ó dára láyé, tí wọn kò sì sin òkú rẹ̀, ọmọ tí a bí lókùú sàn jù ú lọ. +Nítorí òkúmọ yìí wá sinu asán, ó sì pada sinu òkùnkùn. Òkùnkùn bo orúkọ rẹ̀, ẹnìkan kò sì ranti rẹ̀ mọ́. +Kò rí oòrùn rí, kò sì mọ nǹkankan, sibẹsibẹ ó ní ìsinmi; nítorí náà ó sàn ju ẹni tí ó bí ọgọrun-un ọmọ tí ó kú láìrí ẹni sin òkú rẹ̀ lọ. +Bí ó tilẹ̀ gbé ẹgbaa (2,000) ọdún láyé kí ó tó kú, tí kò sì gbádùn ohun rere kankan, ibìkan náà ni gbogbo wọn ń pada lọ. +Gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe, nítorí àtijẹun ni, sibẹsibẹ oúnjẹ kì í yó ni. +Kí ni anfaani tí ọlọ́gbọ́n ní tí ó fi ju òmùgọ̀ lọ? Kí sì ni anfaani tí talaka rí ninu pé ó mọ̀ ọ́n ṣe ní àwùjọ eniyan. +Ó sàn kí ojú ẹni rí nǹkan, ju kí á máa fi ọkàn lépa rẹ̀ lọ. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pẹlu. +Orúkọ rere dára ju òróró olówó iyebíye lọ, ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ ìbí lọ. +Má máa bèèrè pé, “Kí ló dé tí ìgbà àtijọ́ fi dára ju ti ìsinsìnyìí lọ?” Irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ kò mọ́gbọ́n lọ́wọ́. +Ọgbọ́n dára bí ogún, a máa ṣe gbogbo eniyan ní anfaani. +Nítorí pé bí ọgbọ́n ṣe jẹ́ ààbò, bẹ́ẹ̀ ni owó náà jẹ́ ààbò; anfaani ìmọ̀ ni pé, ọgbọ́n a máa dáàbò bo ọlọ́gbọ́n. +Ẹ kíyèsí ọgbọ́n Ọlọrun, nítorí pé, ta ló lè tọ́ ohun tí ó bá dá ní wíwọ́? +Máa yọ̀ nígbà tí ó bá dára fún ọ, ṣugbọn nígbà tí nǹkan kò bá dára, máa ranti pé Ọlọrun ló ṣe mejeeji. Nítorí náà, eniyan kò lè mọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. +Ninu gbogbo ìgbé-ayé asán mi, mo ti rí àwọn nǹkan wọnyi: Mo ti rí olódodo tí ó ṣègbé ninu òdodo rẹ̀, mo sì ti rí eniyan burúkú tí ẹ̀mí rẹ̀ gùn, pẹlu bí ó ti ń ṣe ibi. +Má jẹ́ kí òdodo rẹ pọ̀ jù, má sì gbọ́n ní àgbọ́njù; kí ni o fẹ́ pa ara rẹ fún? +Má ṣe burúkú jù, má sì jẹ́ òmùgọ̀. Ki ni o fẹ́ pa ara rẹ lọ́jọ́ àìpé fún? +Di ekinni mú ṣinṣin, má sì jẹ́ kí ekeji bọ́ lọ́wọ́ rẹ; nítorí ẹni tí ó bá bẹ̀rù Ọlọrun yóo ní ìlọsíwájú. +Ọgbọ́n yóo mú ọlọ́gbọ́n lágbára ju ọba mẹ́wàá lọ láàrin ìlú. +Ó dára láti lọ sí ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ju ati lọ sí ibi àsè lọ,nítorí pé àwọn alààyè gbọdọ̀ máa rán ara wọn létí péikú ni òpin gbogbo eniyan.Gbogbo alààyè ni wọ́n gbọdọ̀ máa fi èyí sọ́kàn. +Kò sí olódodo kan láyé tí ń ṣe rere, tí kò lẹ́ṣẹ̀. +Má máa fetí sí gbogbo nǹkan tí àwọn eniyan bá wí, kí o má baà gbọ́ pé iranṣẹ rẹ kan ń bú ọ. +Ìwọ náà mọ̀ ní ọkàn rẹ pé, ní ọpọlọpọ ìgbà ni ìwọ náà ti bú eniyan rí. +Gbogbo nǹkan wọnyi ni mo ti fi ọgbọ́n wádìí. Mo sọ ninu ara mi pé, “Mo fẹ́ gbọ́n,” ṣugbọn ọgbọ́n jìnnà sí mi. +Ta ló lè ṣe àwárí ohun tó jìnnà gbáà, tí ó jinlẹ̀ gan-an? +Mo tún pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́, láti ṣe ìwádìí, ati láti wá ọgbọ́n, kí n mọ gbogbo nǹkan, ati ibi tí ń bẹ ninu ìwà òmùgọ̀, ati àìlóye tí ó wà ninu ìwà wèrè. +Mo rí i pé, nǹkankan wà tí ó burú ju ikú lọ: òun ni obinrin oníṣekúṣe. Ọkàn rẹ̀ dàbí tàkúté ati àwọ̀n, tí ọwọ́ rẹ̀ dàbí ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọrun kò ní bọ́ sọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kó sinu tàkúté rẹ̀. +Ohun tí mo rí nìyí, lẹ́yìn tí mo farabalẹ̀ ṣe ìwádìí pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, +òun ni mò ń rò nígbà gbogbo, sibẹ, ó ṣì ń rú mi lójú: Láàrin ẹgbẹrun ọkunrin a lè rí ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ eniyan rere, ṣugbọn ninu gbogbo àwọn obinrin, kò sí ẹnìkan. +Ẹ̀kọ́ tí mo rí kọ́ ni pé rere ni Ọlọrun dá eniyan, ṣugbọn àwọn ni wọ́n wá oríṣìíríṣìí ọ̀nà àrékérekè fún ara wọn. +Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ; lóòótọ́ ó lè mú kí ojú fàro, ṣugbọn a máa mú ayọ̀ bá ọkàn. +Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn ọkàn òmùgọ̀ wà ní ibi ìgbádùn. +Ó dára kí eniyan fetí sí ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju láti máa gbọ́ orin ìyìn àwọn òmùgọ̀ lọ. +Bí ẹ̀gún ṣe máa ń ta ninu iná, lábẹ́ ìkòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rín òmùgọ̀ rí. Asán ni èyí pẹlu. +Dájúdájú, ìwà ìrẹ́jẹ a máa mú kí ọlọ́gbọ́n eniyan dàbí òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a sì máa ra eniyan níyè. +Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ, sùúrù sì dára ju ìwà ìgbéraga lọ. +Má máa yára bínú, nítorí àyà òmùgọ̀ ni ibinu dì sí. +Èrò nípa Ìgbé-Ayé. +Ta ló dàbí ọlọ́gbọ́n? Ta ló sì mọ ìtumọ̀ nǹkan? Ọgbọ́n ní ń mú kí ojú ọlọ́gbọ́n máa dán, á mú kí ó tújúká kí ó gbàgbé ìṣòro. +Mo rí àwọn ẹni ibi tí a sin sí ibojì. Nígbà ayé wọn, wọn a ti máa ṣe wọlé-wọ̀de ní ibi mímọ́, àwọn eniyan a sì máa yìn wọ́n, ní ìlú tí wọn tí ń ṣe ibi. Asán ni èyí pẹlu. +Nítorí pé wọn kì í tètè dá ẹjọ́ àwọn ���ni ibi, ni ọkàn ọmọ eniyan fi kún fún ìwà ibi. +Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tilẹ̀ ṣe ibi ní ọpọlọpọ ìgbà tí ọjọ́ rẹ̀ sì gùn, sibẹsibẹ mo mọ̀ pé yóo dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọrun. +Ṣugbọn kò ní dára fún ẹni ibi, bẹ́ẹ̀ sì ni ọjọ́ rẹ̀ kò ní gùn bí òjìji, nítorí kò bẹ̀rù Ọlọrun. +Ohun asán kan tún wà tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé yìí, a rí àwọn olódodo tí wọn ń jẹ ìyà àwọn eniyan burúkú, tí eniyan burúkú sì ń gba èrè olódodo, asán ni èyí pẹlu. +Ìmọ̀ràn mi ni pé, kí eniyan máa gbádùn, nítorí kò sí ire kan tí ọmọ eniyan tún ń ṣe láyé ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lọ; nítorí èyí ni yóo máa bá a lọ ní gbogbo ọjọ́ tí Ọlọrun fún un láyé. +Nígbà tí mo fi tọkàntọkàn pinnu láti wá ọgbọ́n ati láti wo iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní ayé, bí eniyan kì í tíí fi ojú ba oorun tọ̀sán-tòru, +mo wá rí gbogbo iṣẹ́ Ọlọrun pé, kò sí ẹni tí ó lè rí ìdí iṣẹ́ tí ó ń ṣe láyé. Kò sí bí eniyan ti lè ṣe làálàá tó, kò lè rí ìdí rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ń sọ pé àwọn mọ iṣẹ́ OLUWA, sibẹsibẹ wọn kò lè rí ìdí rẹ̀. +Pa òfin ọba mọ́, má sì fi ìwàǹwára jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọrun. +Tètè kúrò níwájú ọba, má sì pẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá ń di ibinu, nítorí pé ohun tí ó bá wù ú ló lè ṣe. +Nítorí pé ohun tí ọba bá sọ ni abẹ gé. Bí ọba bá ṣe nǹkan, ta ló tó yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ wò? +Ẹni tí ó bá ń pa òfin mọ́ kò ní rí ibi; ọlọ́gbọ́n mọ àkókò ati ọ̀nà tí ó yẹ láti gbà ṣe nǹkan. +Gbogbo nǹkan ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wahala wọ ẹ̀dá lọ́rùn. +Ẹnikẹ́ni kò mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la; ta ló lè sọ fún eniyan bí yóo ṣe ṣẹlẹ̀? +Kò sí ẹni tí ó lágbára láti dá ẹ̀mí dúró, tabi láti yí ọjọ́ ikú pada, gbèsè ni ikú, kò sí ẹni tí kò ní san án; ìwà ibi àwọn tí ń ṣe ibi kò sì le gbà wọ́n sílẹ̀. +Nígbà tí mo fi tọkàntọkàn pinnu láti ṣàkíyèsí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé, mo rí i pé ọpọlọpọ eniyan ní ń lo agbára wọn lórí àwọn ẹlòmíràn sí ìpalára ara wọn. +Gbọ́ràn Sọ́ba Lẹ́nu. +Gbogbo nǹkan wọnyi ni mo fi sọ́kàn. Mo yẹ gbogbo rẹ̀ wò, bí ó ti jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni àwọn olódodo, àwọn ọlọ́gbọ́n, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn wà. Bí ti ìfẹ́ ni, bí ti ìkórìíra ni, ẹnìkan kò mọ̀. Asán ni gbogbo ohun tí ó wà níwájú wọn. +Ohunkohun tí o bá ti dáwọ́ lé, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é nítorí, kò sí iṣẹ́, tabi èrò, tabi ìmọ̀, tabi ọgbọ́n, ní isà òkú tí ò ń lọ. +Bákan náà, mo rí i pé, láyé, ẹni tí ó yára, tí ó lè sáré, lè má borí ninu eré ìje, alágbára lè jagun kó má ṣẹgun, ọlọ́gbọ́n lè má rí oúnjẹ jẹ, eniyan lè gbọ́n kó lóye, ṣugbọn kí ó má lówó lọ́wọ́, ẹni tí ó mọ iṣẹ́ ṣe sì lè má ní ìgbéga, àjálù ati èèṣì lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni. +Kò sí ẹni tí ó mọ àkókò tirẹ̀. Bíi kí ẹja kó sinu àwọ̀n burúkú, tabi kí ẹyẹ kó sinu pańpẹ́, ni tàkúté ibi ṣe máa ń mú eniyan, nígbà tí àkókò ibi bá dé bá wọn. +Mo tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n kan nílé ayé, ó sì jẹ́ ohun ribiribi lójú mi. +Ìlú kékeré kan wà, tí eniyan kò pọ̀ ninu rẹ̀, ọba ńlá kan wà, ó dótì í, ó sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀. +Ọkunrin ọlọ́gbọ́n kan wà níbẹ̀ tí ó jẹ́ talaka, ó gba ìlú náà sílẹ̀ pẹlu ọgbọ́n rẹ̀, ṣugbọn ẹnìkan kò ranti talaka náà mọ́. +Sibẹsibẹ, mo rí i pé ọgbọ́n ju agbára lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ka ọgbọ́n ọkunrin yìí kún, tí kò sì sí ẹni tí ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. +Ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ tí ọlọ́gbọ́n bá sọ, ó dára ju igbe aláṣẹ láàrin àwọn òmùgọ̀ lọ. +Ọgbọ́n dára ju ohun ìjà ogun lọ, ṣugbọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kanṣoṣo a máa ba nǹkan ribiribi jẹ́. +Nítorí nǹkankan náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn: ati olódodo ati ẹlẹ́ṣẹ̀, ati eniyan rere ati eniyan burúkú, ati ẹni mímọ́, ati ẹni tí kò mọ́, ati ẹni tí ń rúbọ ati ẹni tí kì í rú. Bí eniyan rere ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹlẹ́ṣẹ̀ náà rí. Bákan náà ni ẹni tí ń búra ati ẹni tí ó takété sì ìbúra. +Nǹkankan tí ó burú, ninu àwọn nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé ni pé, ìpín kan náà ni gbogbo ọmọ aráyé ní, ọkàn gbogbo eniyan kún fún ibi, ìwà wèrè sì wà lọ́kàn wọn; lẹ́yìn náà, wọn a sì kú. +Ṣugbọn ìrètí ń bẹ fún ẹni tí ó wà láàyè, nítorí pé ààyè ajá wúlò ju òkú kinniun lọ. +Nítorí alààyè mọ̀ pé òun óo kú, ṣugbọn òkú kò mọ nǹkankan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní èrè kan mọ́, a kò sì ní ranti wọn mọ́. +Ìfẹ́, ati ìkórìíra, ati ìlara wọn ti parun, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ laelae ninu ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé. +Máa lọ fi tayọ̀tayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ, sì máa mu ọtí waini rẹ pẹlu ìdùnnú, nítorí Ọlọrun ti fi ọwọ́ sí ohun tí ò ń ṣe. +Máa wọ aṣọ àríyá nígbà gbogbo, sì máa fi òróró pa irun rẹ dáradára. +Máa gbádùn ayé pẹlu aya rẹ, olólùfẹ́ rẹ, ní gbogbo ọjọ́ asán tí Ọlọrun fún ọ nílé ayé. Nítorí ìpín tìrẹ nìyí láyé ninu làálàá tí ò ń ṣe. +Èrò lórí Ọgbọ́n ati Ìwà Òmùgọ̀. +Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu nípa ìfẹ́ Ọlọrun, ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Efesu, àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi Jesu. +Èyí ni pé, nígbà tí àkókò bá tó, kí ó lè ṣe ohun gbogbo ní àṣeparí ninu Kristi nígbà tí ó bá yá, ìbáà ṣe àwọn ohun tí ó wà ninu àwọn ọ̀run, tabi àwọn ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, kí ó lè sọ wọ́n di ọ̀kan ninu Kristi. +Nípasẹ̀ Kristi kan náà ni Ọlọrun ti pín wa ní ogún. Ètò tí ó ti ṣe fún wa nìyí, òun tí ó ń mú ohun gbogbo ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀. +Àyọrísí gbogbo èyí ni pé kí àwa Juu tí a kọ́kọ́ ní ìrètí ninu Kristi lè yìn ín lógo. +Ninu Kristi kan náà ni ẹ̀yin tí kì í ṣe Juu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́, tíí ṣe ìyìn rere ìgbàlà yín tí ẹ gbàgbọ́. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni Ọlọrun ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ṣe ìlérí fun yín bí èdìdì. +Ẹ̀mí Mímọ́ yìí jẹ́ onídùúró ogún tí a óo gbà nígbà tí Ọlọrun bá dá àwọn eniyan rẹ̀ nídè, kí á lè yin Ọlọrun lógo. +Nítorí èyí, láti ìgbà tí mo ti gbọ́ nípa igbagbọ yín ninu Oluwa Jesu, ati ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn onigbagbọ, èmi náà +kò sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, mo sì ń ranti yín ninu adura mi. +Mò ń gbadura pé kí Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba ológo, lè fun yín ní ẹ̀mí ọgbọ́n, kí ó sì jẹ́ kí ẹ ní ìmọ̀ tí ó kún nípa òun alára. +Mo sì tún ń gbadura pé kí ó lè là yín lójú ẹ̀mí, kí ẹ lè mọ ìrètí tí ó ní tí ó fi pè yín, kí ẹ sì lè mọ ògo tí ó wà ninu ogún rẹ̀ tí yóo pín fun yín pẹlu àwọn onigbagbọ, +ati bí agbára rẹ̀ ti tóbi tó fún àwa tí a gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ títóbi agbára rẹ̀. +Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín. +Ó fi agbára yìí hàn ninu Kristi nígbà tí ó jí i dìde ninu òkú, tí ó mú un jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lọ́run. +Ó ga ju gbogbo àwọn ọlọ́lá ati aláṣẹ ati àwọn alágbára ati àwọn olóye tí wọ́n wà lójú ọ̀run lọ. Ó tún ga ju gbogbo orúkọ tí eniyan lè dá lọ, kì í ṣe ní ayé yìí nìkan, ṣugbọn ati ní ayé tí ń bọ̀ pẹlu. +Ọlọrun ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ Kristi yìí kan náà ó fi ṣe orí fún gbogbo ìjọ onigbagbọ. +Ìjọ ni ara Kristi, Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun gbogbo. Òun ni ó ń mú ohun gbogbo kún. +Ẹ jẹ́ kí á fi ìyìn fún Ọlọrun Baba Oluwa wa Jesu Kristi, tí ó ti fi ọpọlọpọ ibukun ti ẹ̀mí fún wa lọ́run nípasẹ̀ Kristi. +Òun ni ó yàn wá nípasẹ̀ Kristi kí ó tó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀. Ó yàn wá kí á lè jẹ́ ẹni tí a yà sọ́tọ̀, tí kò ní àléébù níwájú rẹ̀, tí ó sì kún fún ìfẹ́. +Ó ti pinnu tẹ́lẹ̀ láti fi wá ṣe ọmọ rẹ̀ nípasẹ̀ Jesu Kristi, ohun tí ó fẹ́ tí inú rẹ̀ sì dùn sí nìyí; +kí á lè mọyì ẹ̀bùn rẹ̀ tí ó lógo tí ó fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́ nípasẹ̀ Kristi àyànfẹ́ rẹ̀. +Nípasẹ̀ Kristi ni a ti ní ìdáǹdè nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti rí ìdáríjì gbà fún àwọn ìrékọjá wa, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. +A ní oore-ọ̀fẹ́ yìí lọpọlọpọ!Ó fún wa ní gbogbo ọgbọ́n ati òye. +Ó jẹ́ kí á mọ àṣírí ìfẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètò tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ tí ó ti ṣe ninu Kristi. +Ìkíni. +Nígbà kan rí ẹ jẹ́ òkú ninu ìwàkiwà ati ẹ̀ṣẹ̀ yín. +Nítorí òun ni ó dá wa bí a ti rí, ó dá wa fún iṣẹ́ rere nípasẹ̀ Kristi Jesu, àwọn iṣẹ́ tí Ọlọrun ti ṣe tẹ́lẹ̀, pé kí á máa ṣe. +Nítorí náà, ẹ ranti pé nígbà kan rí, ẹ jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí ipò tí a bi yín sí. Àwọn tí wọ́n kọlà ti ara, tí wọ́n fi ọwọ́ kọ sì ń pè yín ní aláìkọlà. +Nígbà náà ẹ wà ní ipò ẹni tí kò mọ Kristi. Ẹ jẹ́ àjèjì sí àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ Israẹli. Àwọn majẹmu tí ó ní ìlérí Ọlọrun ninu sì tún ṣe àjèjì si yín. Ẹ wà ninu ayé láìní ìrètí ati láìní Ọlọrun. +Ṣugbọn nisinsinyii, ninu Kristi Jesu, ẹ̀yin tí ẹ wà ní ọ̀nà jíjìn nígbà kan rí, ti súnmọ́ ìtòsí nípa ẹ̀jẹ̀ tí Kristi ta sílẹ̀. +Nítorí pé Kristi yìí ni alaafia wa. Òun ni ó sọ àwọn tí wọ́n kọlà ati àwọn tí kò kọlà di ọ̀kan. Nígbà tí ó gbé ara eniyan wọ̀, ó wó ògiri ìkélé tí ó wà láàrin wọn tí wọ́n fi ń yan ara wọn lódì. +Ó sọ òfin ati àwọn ìlànà ati àṣẹ di nǹkan yẹpẹrẹ, kí ó lè sọ àwọn mejeeji di ẹ̀dá titun kan náà ninu ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú alaafia wá sáàrin wọn. +Ó làjà láàrin àwọn mejeeji, ó sọ wọ́n di ara kan lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa agbelebu. Ó ti mú odì yíyàn dópin lórí agbelebu. +Nígbà tí ó dé, ó waasu ìyìn rere alaafia fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní ọ̀nà jíjìn, ó sì waasu ìyìn rere alaafia fún àwọn tí ó wà nítòsí. +Nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa mejeeji ṣe rí ààyè láti dé ọ̀dọ̀ Baba nípa Ẹ̀mí kan náà. +Nítorí náà, ẹ kì í tún ṣe àlejò ní ìlú àjèjì mọ́, ṣugbọn ẹ jẹ́ ọmọ-ìbílẹ̀ pẹlu àwọn onigbagbọ, ẹ sì di mọ̀lẹ́bí ninu agbo-ilé Ọlọrun. +Nígbà náà ẹ̀ ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni ti ayé yìí, ẹ̀ ń gbọ́ràn sí aláṣẹ àwọn ẹ̀mí tí ó wà ninu òfuurufú lẹ́nu, àwọn ẹ̀mí wọnyi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí ninu àwọn ọmọ tí kò gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu. +Lórí àwọn aposteli ati àwọn wolii ni a ti fi ìpìlẹ̀ ìdílé yìí lélẹ̀, Kristi Jesu fúnrarẹ̀ sì ni òkúta igun ilé. +Òun ni ó mú kí gbogbo ilé dúró dáradára, tí ó sì mú un dàgbà láti di ilé ìsìn mímọ́ fún Oluwa. +Ẹ̀mí ń kọ́ àwa ati ẹ̀yin papọ̀ ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi kí á lè di ibùgbé Ọlọrun. +Gbogbo àwa yìí náà ti wà lára irú wọn rí, nígbà tí à ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, tí à ń ṣe àwọn nǹkan tí ara bá fẹ́ ati àwọn ohun tí ọkàn bá ti rò. Nígbà náà, nípa ti ẹ̀dá ara, àwa náà wà ninu àwọn ọmọ tí Ọlọrun ìbá bínú sí, gẹ́gẹ́ bí àwọn eniyan yòókù. +Ṣugbọn nítorí ìfẹ́ ńlá tí Ọlọrun tí ó ní àánú pupọ ní sí wa, +ó sọ wá di alààyè pẹlu Kristi nígbà tí a ti di òkú ninu ìwàkíwà wa. Oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là. +Ọlọrun tún jí wa dìde pẹlu Kristi Jesu, ó wá fi wá jókòó pẹlu rẹ̀ lọ́run, +kí ó lè fihàn ní àkókò tí ó ń bọ̀ bí ọlá oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ti tóbi tó, nípa àánú tí ó ní sí wa ninu Kristi Jesu. +Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là nípa igbagbọ. Kì í ṣe nítorí iṣẹ́, ẹ̀bùn Ọlọrun ni. Kì í ṣe ìtorí iṣẹ́ tí eniyan ṣe, kí ẹnikẹ́ni má baà máa gbéraga. +Láti Inú Ikú sí Inú Ìyè. +Ìdí rẹ̀ nìyí tí èmi Paulu fi di ẹlẹ́wọ̀n fún Kristi Jesu nítorí ti ẹ̀yin tí ẹ kì í ṣe Juu. +kí ó lè sọ ọ́ di mímọ̀ ní àkókò yìí láti ọ̀dọ̀ ìjọ, kí ó sì lè fihan àwọn alágbára ati àwọn aláṣẹ tí ó wà ninu àwọn ọ̀run bí ọgbọ́n Ọlọrun ti pọ̀ tó ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. +Ọlọrun ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ètò rẹ̀, láti ayérayé, tí ó mú ṣẹ ninu Kristi Jesu Oluwa wa. +Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìgboyà láti dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun. A sì ní ìdánilójú pé a ti rí ààyè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nípa igbagbọ. +Nítorí èyí, mò ń gbadura pé kí ọkàn yín má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìpọ́njú tí mò ń rí nítorí yín. Ohun ìṣògo ni èyí jẹ́ fun yín. +Nítorí èyí ni mo ṣe ń fi ìkúnlẹ̀ gbadura sí Baba, +tí à ń fi orúkọ rẹ̀ pe gbogbo ìdílé lọ́run ati láyé. +Mò ń gbadura pé, gẹ́gẹ́ bíi títóbi ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní agbára Ẹ̀mí rẹ̀ tí yóo fún ọkàn yín ní okun; +kí Kristi fi ọkàn yín ṣe ilé nípa igbagbọ kí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu ìfẹ́, kí ìpìlẹ̀ ìgbé-ayé yín jẹ́ ti ìfẹ́, +kí ẹ lè ní agbára, pẹlu gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun, láti mọ bí ìfẹ́ Kristi ti gbòòrò tó, bí ó ti gùn tó, bí ó ti ga tó, ati bí ó ti jìn tó; +kí ẹ lè mọ bí ìfẹ́ Kristi ti tayọ ìmọ̀ ẹ̀dá tó, kí ẹ sì lè kún fún gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọrun. +Ẹ óo ṣá ti gbọ́ nípa iṣẹ́ tí Ọlọrun fi fún mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ láti ṣe fun yín. +Ògo ni fún ẹni tí ó lè ṣe ju gbogbo nǹkan tí à ń bèèrè, ati ohun gbogbo tí a ní lọ́kàn lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ ninu wa. +Kí ògo yìí wà fún un ninu ìjọ ati ninu Kristi Jesu láti ìrandíran títí laelae. Amin. +Ọlọrun ni ó fi àṣírí yìí hàn mí lójú ìran, gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ọ́ sinu ìwé ní ṣókí tẹ́lẹ̀. +Nígbà tí ẹ bá kà á, ẹ óo rí i pé mo ní òye àṣírí Kristi, +tí Ọlọrun kò fihan àwọn ọmọ eniyan ní ìgbà àtijọ́, ṣugbọn tí ó fihan àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ ati àwọn wolii rẹ̀ nisinsinyii, ninu ẹ̀mí. +Àṣírí yìí ni pé àwọn tí kì í ṣe Juu ní anfaani láti pín ninu ogún pẹlu àwọn Juu, ara kan náà sì ni wọ́n pẹlu àwọn tí wọ́n jọ ní ìlérí ninu Kristi Jesu nípasẹ̀ ìyìn rere rẹ̀. +Èyí ni iṣẹ́ tí a fi fún mi nípa ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀. +Nítorí èmi tí mo kéré jùlọ ninu gbogbo àwọn onigbagbọ ni Ọlọrun fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, pé kí n máa waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa àwámárìídìí ọrọ̀ Kristi. +Ati pé kí n ṣe àlàyé nípa ètò àṣírí yìí, tí Ọlọrun ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́, +Iṣẹ́ Paulu láàrin Àwọn Tí Kì í Ṣe Juu. +Nítorí náà, èmi tí mo di ẹlẹ́wọ̀n nítorí ti Oluwa, ń bẹ̀ yín pé kí ẹ máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, bí irú ìpè tí Ọlọrun pè yín. +Òun kan náà tí ó wá sí ìsàlẹ̀ ni ó lọ sí òkè, tí ó tayọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́run, kí ó lè sọ gbogbo nǹkan di kíkún. +Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti jẹ́ aposteli, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ wolii, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ ajíyìnrere, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ alufaa ati olùkọ́ni. +Àwọn ẹ̀bùn wọnyi wà fún lílò láti mú kí ara àwọn eniyan Ọlọrun lè dá ṣáṣá kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, ati láti mú kí ara Kristi lè dàgbà. +Báyìí ni gbogbo wa yóo fi dé ìṣọ̀kan ninu igbagbọ ati ìmọ̀ Ọmọ Ọlọrun, tí a óo fi di géńdé, tí a óo fi dàgbà bí Kristi ti dàgbà. +A kì í tún ṣe ọmọ-ọwọ́ mọ́, tí ìgbì yóo máa bì sọ́tùn-ún, sósì, tabi tí afẹ́fẹ́ oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àrékérekè àwọn tí wọn ń lo ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ láti fi tan eniyan jẹ yóo máa fẹ́ káàkiri. +Ṣugbọn a óo máa sọ òtítọ́ pẹlu ìfẹ́, a óo máa dàgbà ninu rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, ninu Kristi tíí ṣe orí. +Òun ni ó mú kí gbogbo ẹ̀yà ara wà ní ìṣọ̀kan, tí gbogbo oríkèé-ríkèé ara wa sì wà ní ipò wọn, pẹlu iṣan tí ó mú wọn dúró, tí gbogbo wọn sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ipò olukuluku wọn, tí gbogbo ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan fi ń dàgbà, tí ó ń mú kí gbogbo ara rẹ̀ dàgbà ninu ìfẹ́. +Nítorí náà, mò ń sọ fun yín, mo sì ń bẹ̀ yín ní orúkọ Oluwa pé, kí ẹ má máa hùwà bíi ti àwọn abọ̀rìṣà mọ́, àwọn tí wọn ń hùwà gẹ́gẹ́ bí èrò asán ọkàn wọn. +Ọkàn àwọn yìí ti ṣókùnkùn, ó sì ti yàtọ̀ pupọ sí irú ìgbé-ayé tí Ọlọrun fẹ́. Nítorí òpè ni wọ́n, ọkàn wọn ti le. +Wọn kò bìkítà: wọ́n ti fi ara wọn fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara nípa oríṣìíríṣìí ìwà burúkú nítorí ojúkòkòrò. +Kí ẹ máa hùwà pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ọkàn tútù, kí ẹ sì máa mú sùúrù. Kí ẹ máa fi ìfẹ́ bá ara yín lò nípa ìfaradà. +Ṣugbọn a kò kọ́ ẹ̀yin bẹ́ẹ̀ nípa Kristi. +Ẹ ti gbọ́ nípa Jesu, a sì ti fi òtítọ́ rẹ̀ kọ yín, +pé kí ẹ jìnnà sí irú ìwà àtijọ́ tí ẹ ti ń hù, ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tíí máa tan eniyan lọ sinu ìparun. +Kí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ yín di ẹni titun ninu ọkàn yín. +Kí ẹ wá gbé ẹni titun nnì tí Ọlọrun dá wọ̀, kí ẹ lè máa ṣe òdodo, kí ẹ sì máa hu ìwà mímọ́ ninu òtítọ́. +Nítorí náà, ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀. Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín máa bá ẹnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí gbogbo wa jẹ́ ẹ̀yà ara kan náà. +Bí ẹ bá bínú, ẹ má jẹ́ kí ibinu mu yín dẹ́ṣẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ ba yín ninu ibinu. +Ẹ má fi ààyè gba Èṣù. +Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀ kí ó kúkú gbìyànjú láti fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere, kí òun náà lè ní ohun tí yóo fún àwọn aláìní. +Ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ kankan kò gbọdọ̀ ti ẹnu yín jáde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rere, tí ó lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ nígbàkúùgbà ni kí ẹ máa sọ jáde lẹ́nu. Èyí yóo ṣe àwọn tí ó bá gbọ́ ní anfaani. +Ẹ ní ìtara láti pa ìṣọ̀kan ti Ẹ̀mí mọ́ ninu alaafia tí ó so yín pọ̀. +Ẹ má kó ìbànújẹ́ bá Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọrun, tí Ọlọrun fi ṣèdìdì yín títí di ọjọ́ ìràpadà. +Ẹ níláti mú gbogbo inú burúkú, ìrúnú, ibinu, ariwo ati ìsọkúsọ kúrò láàrin yín ati gbogbo nǹkan burúkú. +Ẹ máa ṣoore fún ara yín, ẹ ní ojú àánú; kí ẹ sì máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti dáríjì yín nípasẹ̀ Kristi. +Ara kan ni ó wà, ati Ẹ̀mí kan, gẹ́gẹ́ bí ìpè tí a ti pè yín ti jẹ́ ti ìrètí kan. +Oluwa kan ṣoṣo ni ó wà, ati igbagbọ kan, ati ìrìbọmi kan. +Ọlọrun kan ni ó wà, tíí ṣe Baba gbogbo eniyan, òun ni olórí ohun gbogbo, tí ó ń ṣiṣẹ́ ninu ohun gbogbo, tí ó sì wà ninu ohun gbogbo. +Ṣugbọn ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ẹ̀bùn tí Kristi fi fún wa. +Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé, “Nígbà tí ó lọ sí òkè ọ̀run,ó kó àwọn ìgbèkùn lẹ́yìn,ó sì fi ẹ̀bùn fún àwọn eniyan.” +Nígbà tí ó sọ pé, “Ó lọ sí òkè ọ̀run,” ìtumọ̀ èyí kò lè yéni tóbẹ́ẹ̀ bí kò bá jẹ́ pé ó ti kọ́kọ́ wá sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. +Ìṣọ̀kan Ara Kristi. +Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ, ẹ fi ìwà jọ Ọlọrun. +Kí ẹ máa wádìí ohun tí yóo wu Oluwa. +Ẹ má ṣe bá àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ òkùnkùn tí kò léso rere kẹ́gbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá wọn wí. +Nítorí àwọn ohun tí wọn ń ṣe níkọ̀kọ̀ tilẹ̀ ti eniyan lójú láti sọ. +Nítorí gbogbo nǹkan tí ìmọ́lẹ̀ bá tàn sí níí máa hàn kedere. +Ohun gbogbo tí ó bá hàn kedere di ìmọ́lẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ orin kan ti sọ, pé,“Dìde, ìwọ tí ò ń sùn;jí dìde kúrò ninu òkú,Kristi yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ lára.” +Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra bí ẹ ti ń hùwà. Ẹ má ṣe hùwà bí ẹni tí kò gbọ́n, ṣugbọn ẹ hùwà bí ọlọ́gbọ́n. +Ẹ lo gbogbo àkókò yín dáradára nítorí àkókò tí a wà yìí burú. +Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ aṣiwèrè, ṣugbọn kí ẹ máa fi òye gbé ohun tíí ṣe ìfẹ́ Oluwa. +Ẹ má máa mu ọtí yó, òfò ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. +Ẹ máa fi Orin Dafidi ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá bá ara yín sọ̀rọ̀. Ẹ máa kọrin; ẹ máa fi ìyìn fún Oluwa ninu ọ̀kan yín. +Ẹ máa rìn ninu ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ wa, tí ó fi ara òun tìkararẹ̀ rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí Ọlọrun nítorí tiwa. +Ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Baba nígbà gbogbo fún gbogbo nǹkan ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi. +Ẹ máa tẹríba fún ara yín nítorí ọ̀wọ̀ tí ẹ̀ ń bù fún Kristi. +Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín gẹ́gẹ́ bí Oluwa. +Nítorí ọkọ ni olórí aya gẹ́gẹ́ bí Kristi ti jẹ́ olórí ìjọ. Kristi sì ni Olùgbàlà ara rẹ̀ tíí ṣe ìjọ. +Bí ìjọ ti ń bọ̀wọ̀ fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya máa ṣe sí àwọn ọkọ wọn ninu ohun gbogbo. +Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. +Ó ṣe èyí láti yà á sọ́tọ̀. Ó sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó ti fi omi wẹ̀ ẹ́ nípa ọ̀rọ̀ iwaasu. +Kí ó lè mú ìjọ wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó lọ́lá, tí kò ní àléébù kankan, tabi kí ó hunjọ, tabi kí ó ní nǹkan àbùkù kankan, ṣugbọn kí ó lè jẹ́ ìjọ mímọ́ tí kò ní èérí. +Bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ kí àwọn ọkọ fẹ́ràn àwọn aya wọn, bí wọ́n ti fẹ́ràn ara tiwọn. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn aya rẹ̀, òun tìkararẹ̀ ni ó fẹ́ràn. +Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó kórìíra ara rẹ̀. Ńṣe ni eniyan máa ń tọ́jú ara rẹ̀, tí ó sì máa ń kẹ́ ẹ. Bẹ́ẹ̀ ni Kristi ń ṣe sí ìjọ. +Kí á má ṣe gbúròó ìwà àgbèrè, tabi oríṣìíríṣìí ìṣekúṣe, tabi ojúkòkòrò láàrin àwọn eniyan Ọlọrun. +Nítorí ẹ̀yà ara Kristi ni a jẹ́. +Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, pé, “Nítorí náà ni ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, tí yóo darapọ̀ pẹlu aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo wá di ara kan.” +Àṣírí ńlá ni èyí. Mò ń sọ nípa ipò tí Kristi wà sí ìjọ. +Àkàwé yìí ba yín mu. Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níláti fẹ́ràn aya rẹ̀ bí òun tìkararẹ̀. Aya sì níláti bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀. +Ìwà ìtìjú, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tabi àwàdà burúkú kò yẹ yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọpẹ́ sí Ọlọrun ni ó yẹ yín. +Ẹ̀yin alára mọ̀ dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń ṣe àgbèrè, tabi tí ó ń ṣe ìṣekúṣe, tabi tí ó ní ojúkòkòrò, tabi tí ó ń bọ̀rìṣà, tí yóo ní ìpín ninu ìjọba Kristi, tíí ṣe ìjọba Ọlọrun. +Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ. Nítorí irú èyí ni ibinu Ọlọrun fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọràn. +Nítorí náà ẹ má ṣe fi ara wé wọn. +Nítorí nígbà kan, ninu òkùnkùn patapata ni ẹ wà. Ṣugbọn ní àkókò yìí ẹ ti bọ́ sinu ìmọ́lẹ̀ nítorí ẹ ti di ẹni Oluwa. Ẹ máa hùwà bí ọmọ ìmọ́lẹ̀. +Nítorí èso ìmọ́lẹ̀ ni oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere, òdodo ati òtítọ́. +Gbígbé ninu Ìmọ́lẹ̀. +Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó dára. +Ní ìparí, ẹ jẹ́ alágbára ninu Oluwa, kí ẹ fi agbára rẹ̀ ṣe okun yín. +Ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dúró láti dojú kọ èṣù pẹlu ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀. +Nítorí kì í ṣe eniyan ni à ń bá jagun, bíkòṣe àwọn ẹ̀mí burúkú ojú ọ̀run, àwọn aláṣẹ ati àwọn alágbára òkùnkùn ayé yìí. +Nítorí èyí, ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dìde dúró láti jà nígbà tí ọjọ́ ibi bá dé. Nígbà tí ìjà bá sì dópin, kí ẹ lè wà ní ìdúró. +Nítorí náà, ẹ dúró gbọningbọnin. Ẹ fi òtítọ́ ṣe ọ̀já ìgbànú yín. Ẹ fi òdodo bo àyà yín bí apata. +Ẹ jẹ́ kí ìmúrasílẹ̀ láti waasu ìyìn rere alaafia jẹ́ bàtà ẹsẹ̀ yín. +Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, ẹ fi igbagbọ ṣe ààbò yín. Nípa rẹ̀ ni ẹ óo lè fi pa iná gbogbo ọfà amúbíiná tí èṣù ń ta. +Ẹ fi ìgbàlà ṣe fìlà onírin tí ẹ óo máa dé, kí ẹ sì mú idà Ẹ̀mí Mímọ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun. +Ẹ máa gbadura nígbà gbogbo, kí ẹ máa fi gbogbo ẹ̀bẹ̀ yín siwaju Ọlọrun nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí náà, ẹ máa gbadura láì sùn, láì wo, fún gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun. +Ẹ máa gbadura fún èmi gan-an alára, pé kí n lè mọ ohun tí ó yẹ kí n sọ nígbà tí n óo bá sọ̀rọ̀. Ati pé kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ tí àwọn eniyan yóo fi mọ àṣírí ìyìn rere +“Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ.” Èyí níí ṣe òfin kinni pẹlu ìlérí, pé +tí mo jẹ́ ikọ̀ fún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mí. Ẹ gbadura pé kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ bí ó ti yẹ. +Kí ẹ lè mọ bí nǹkan ti ń lọ sí lọ́dọ̀ mi, ati ohun tí mò ń ṣe, Tukikọsi yóo sọ gbogbo rẹ̀ fun yín. Àyànfẹ́ arakunrin ni, ati iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ninu iṣẹ́ Oluwa. +Ìdí tí mo fi rán an si yín ni pé kí ẹ lè mọ bí gbogbo nǹkan ti ń lọ sí lọ́dọ̀ wa, kí ọkàn yín lè balẹ̀. +Kí alaafia ati ìfẹ́ pẹlu igbagbọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati Oluwa Jesu Kristi, kí ó wà pẹlu àwọn onigbagbọ. +Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn Oluwa wa, Jesu Kristi pẹlu ìfẹ́ tí kò lópin. +“Kí ó lè dára fún ọ, ati kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ náà.” +Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú. Títọ́ ni kí ẹ máa tọ́ wọn ninu ẹ̀kọ́ ati ìlànà ti onigbagbọ. +Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí wọ́n jẹ́ oluwa yín nípa ti ara, pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù, pẹlu ọkàn kan gẹ́gẹ́ bí ẹni pé Kristi ni ẹ̀ ń ṣe é fún. +Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń ṣọ́ yín nìkan ni ẹ óo máa ṣiṣẹ́ bí ìgbà tí ẹ fẹ́ gba ìyìn eniyan. Ṣugbọn bí ẹrú Kristi, ẹ máa ṣe ìfẹ́ Ọlọrun láti ọkàn wá. +Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín pẹlu inú dídùn, bí ẹni pé fún Oluwa, kì í ṣe fún eniyan. +Nítorí ẹ mọ̀ pé ohun rere tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá ṣe, olúwarẹ̀ ìbáà jẹ́ ẹrú tabi kí ó jẹ́ òmìnira, yóo rí èrè gbà lọ́dọ̀ Oluwa. +Ẹ̀yin ọ̀gá, bákan náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹrú yín. Ẹ má máa dẹ́rù bà wọ́n. Ẹ ranti pé ati àwọn, ati ẹ̀yin, ẹ ní Oluwa kan lọ́run, tí kì í ṣe ojuṣaaju. +Ọmọ ati Òbí. +Ní àkókò tí Ahasu-erusi jọba ní ilẹ̀ Pasia, ìjọba rẹ̀ tàn dé agbègbè mẹtadinlaadoje (127), láti India títí dé Kuṣi ní ilẹ̀ Etiopia. +Ní ọjọ́ keje, nígbà tí ọba mu ọtí waini tí inú rẹ̀ dùn, ó pàṣẹ fún meje ninu àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ iranṣẹ rẹ̀: Mehumani, Bisita ati Habona, Bigita ati Abagita, Setari ati Kakasi, +pé kí wọ́n lọ mú Ayaba Faṣiti wá siwaju òun, pẹlu adé lórí rẹ̀, láti fi ẹwà rẹ̀ han gbogbo àwọn eniyan ati àwọn olórí, nítorí pé ó jẹ́ arẹwà obinrin. +Ṣugbọn nígbà tí àwọn ìwẹ̀fà tí ọba rán jíṣẹ́ fún un, ó kọ̀, kò wá siwaju ọba. Nítorí náà, inú bí ọba gidigidi, inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ru. +Ọba bá fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n ní òye nípa àkókò, (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ọba máa ń ṣe sí gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òfin ati ìdájọ́. +Àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọn ni: Kaṣena, Ṣetari, ati Adimata, Taṣiṣi ati Meresi, Masena ati Memkani, àwọn ìjòyè meje ní Pasia ati Media. Àwọn ni wọ́n súnmọ́ ọn jù, tí ipò wọn sì ga jùlọ). +Ọba bi wọ́n pé, “Gẹ́gẹ́ bí òfin, kí ni kí á ṣe sí Ayaba Faṣiti, nítorí ohun tí ọba pa láṣẹ, tí ó rán àwọn ìwẹ̀fà sí i pé kí ó ṣe kò ṣe é.” +Memkani bá dáhùn níwájú ọba ati àwọn ìjòyè pé, “Kì í ṣe ọba nìkan ni Faṣiti kò kà sí, bíkòṣe gbogbo àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè ìjọba Ahasu-erusi ọba. +Nǹkan tí Faṣiti ṣe yìí yóo di mímọ̀ fún àwọn obinrin, àwọn náà yóo sì máa fi ojú tẹmbẹlu àwọn ọkọ wọn. Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọba ṣá ti ranṣẹ sí ayaba pé kí ó wá siwaju òun rí, tí ó kọ̀, tí kò lọ.’ +Láti òní lọ, àwọn obinrin, pàápàá àwọn obinrin Pasia ati ti Media, tí wọ́n ti gbọ́ ohun tí Ayaba ṣe yóo máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ sí àwọn ìjòyè. Èyí yóo sì mú kí aifinipeni ati ibinu pọ̀ sí i. +Nítorí náà bí ó bá wu ọba, kí ọba pàṣẹ, kí á sì kọ ọ́ sinu ìwé òfin Pasia ati ti Media, tí ẹnikẹ́ni kò lè yipada, pé Faṣiti kò gbọdọ̀ dé iwájú ọba mọ́, kí ọba sì fi ipò rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó sàn jù ú lọ. +Nígbà tí ó wà lórí oyè ní Susa tíí ṣe olú-ìlú ìjọba rẹ̀, +Nígbà tí a bá kéde òfin yìí jákèjádò agbègbè rẹ, àwọn obinrin yóo máa bu ọlá fún àwọn ọkọ wọn; ọkọ wọn kì báà jẹ́ talaka tabi olówó.” +Inú ọba ati àwọn ìjòyè dùn sí ìmọ̀ràn yìí, nítorí náà ọba ṣe bí Memkani ti sọ. +Ó fi ìwé ranṣẹ sí gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀, ati sí gbogbo agbègbè ati àwọn ẹ̀yà, ní èdè kaluku wọn, pé kí olukuluku ọkunrin máa jẹ́ olórí ninu ilé rẹ̀. +ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè fún àwọn ìjòyè, ati àwọn olórí, àwọn òṣìṣẹ́, ati àwọn olórí ogun Pasia ati ti Media, àwọn eniyan pataki pataki tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ati àwọn gomina agbègbè rẹ̀. +Fún odidi ọgọsan-an (180) ọjọ́ ni ọba fi ń fi ògo ìjọba rẹ̀ hàn, pẹlu ọrọ̀ ati dúkìá rẹ̀. +Lẹ́yìn náà, ọba se àsè ní àgbàlá ààfin fún ọjọ́ meje, fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní Susa, àtàwọn talaka, àtàwọn eniyan ńláńlá. +Wọ́n ṣe ọgbà náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró ati aṣọ funfun. Wọ́n fi òwú funfun ati òwú àlàárì ṣe okùn, wọ́n fi so wọ́n mọ́ òrùka fadaka, wọ́n gbé wọn kọ́ sára òpó òkúta mabu. Wúrà ati fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn àga tí ó wà ninu ọgbà. Òkúta mabu pupa ati aláwọ̀ aró ni wọ́n fi ṣe gbogbo ọ̀dẹ̀dẹ̀, tí gbogbo wọn ń dán gbinringbinrin. +Wọ́n ń fi oríṣìíríṣìí ife wúrà mu ọtí, ọba sì pèsè ọtí lọpọlọpọ gẹ́gẹ́ bí ipò ọlá ńlá rẹ̀. +Àṣẹ ọba ni wọ́n tẹ̀lé nípa ọ̀rọ̀ ọtí mímu. Wọn kò fi ipá mú ẹnikẹ́ni, nítorí pé ọba ti pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ ààfin pé ohun tí olukuluku bá fẹ́ ni kí wọn fi tẹ́ ẹ lọ́rùn. +Ayaba Faṣiti pàápàá se àsè fún àwọn obinrin ní ààfin ọba Ahasu-erusi. +Ayaba Faṣiti Rí Ahasu-erusi Ọba Fín. +Ọba Ahasu-erusi pàṣẹ pé kí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jìnnà ati àwọn tí wọn ń gbé etíkun máa san owó orí. +Gbogbo iṣẹ́ agbára ati ipá rẹ̀, ati bí ó ṣe gbé Modekai ga sí ipò ọlá, ni a kọ sinu ìwé ìtàn àwọn ọba Media ati ti Pasia. +Modekai tíí ṣe Juu ni igbákejì sí Ahasu-erusi ọba. Ó tóbi, ó sì níyì pupọ láàrin àwọn Juu, nítorí pé ó ń wá ire àwọn eniyan rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ alaafia fún gbogbo wọn. +Títóbi Ahasu-erusi ati Modekai. +Nígbà tí ó yá, tí ibinu ọba rọlẹ̀, ó ranti ohun tí Faṣiti ṣe, ati àwọn àṣẹ tí òun pa nípa rẹ̀. +Ẹsita kò sọ inú ẹ̀yà tí òun ti wá, tabi ìdílé rẹ̀, fún ẹnikẹ́ni nítorí pé Modekai ti kìlọ̀ fún un pé kí ó má ṣe sọ nǹkankan nípa rẹ̀. +Lojoojumọ ni Modekai máa ń rìn sókè sódò níwájú àgbàlá ibi tí àwọn ayaba ń gbé, láti bèèrè alaafia Ẹsita, ati bí ó ti ń ṣe sí. +Kí wundia kankan tó lè lọ rí ọba, ó gbọdọ̀ kọ́ wà ninu ilé fún oṣù mejila, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn obinrin wọn. Oṣù mẹfa ni wọ́n fi ń kun òróró ati òjíá, wọn á sì fi oṣù mẹfa kun òróró olóòórùn dídùn ati ìpara àwọn obinrin. +Nígbà tí wundia kan bá ń lọ siwaju ọba, lẹ́yìn tí ó ba ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó yẹ, ó lè gba ohunkohun tí ó bá fẹ́ mú lọ láti ilé àwọn ayaba. +Yóo lọ sibẹ ní alẹ́, ní òwúrọ̀ yóo pada wá sí ilé keji tí àwọn ayaba ń lò, tí ó wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣaaṣigasi, ìwẹ̀fà tí ó ń tọ́jú àwọn obinrin ọba. Kò tún ní pada lọ rí ọba mọ́, àfi bí inú ọba bá dùn sí i tí ó sì ranṣẹ pè é. +Nígbà tí ó tó àkókò fún Ẹsita, ọmọ Abihaili ẹ̀gbọ́n Modekai, láti lọ rí ọba, Ẹsita kò bèèrè nǹkankan ju ohun tí Hegai, ìwẹ̀fà ọba tí ń tọ́jú àwọn ayaba, sọ fún un pé kí ó mú lọ. Ẹsita rí ojurere lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n rí i. +Wọ́n mú Ẹsita lọ sọ́dọ̀ ọba Ahasu-erusi ní ààfin rẹ̀ ní oṣù Tebeti, tíí ṣe oṣù kẹwaa, ní ọdún keje ìjọba rẹ̀. +Ọba fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo àwọn obinrin yòókù lọ, ó sì rí ojurere ọba ju gbogbo àwọn wundia yòókù lọ. Ọba gbé adé lé e lórí, ó sì fi ṣe ayaba dípò Faṣiti. +Ọba bá se àsè ńlá fún àwọn olóyè ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ nítorí Ẹsita. Ó fún gbogbo eniyan ní ìsinmi, ó sì fún wọn ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn. +Nígbà tí àwọn wundia péjọ ní ẹẹkeji, Modekai jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin. +Àwọn iranṣẹ ọba tí wọ́n súnmọ́ ọn tímọ́tímọ́ bá sọ fún un pé, +Ṣugbọn Ẹsita kò sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ẹ̀yà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Modekai ti pàṣẹ fún un, nítorí ó gbọ́ràn sí Modekai lẹ́nu, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe nígbà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú rẹ̀. +Ní àkókò náà, nígbà tí Modekai jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin, meji ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà: Bigitana ati Tereṣi, ń bínú sí ọba, wọ́n sì ń dìtẹ̀ láti pa Ahasu-erusi ọba. +Ṣugbọn Modekai gbọ́ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sọ fún Ẹsita, ayaba, Ẹsita bá tètè lọ sọ fún ọba pé Modekai ni ó gbọ́ nípa ète náà tí ó sọ fún òun. +Nígbà tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n sì rí i pé òtítọ́ ni, wọ́n so àwọn ọlọ̀tẹ̀ mejeeji náà kọ́ sórí igi. Wọ́n sì kọ gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ ninu ìwé ìtàn ìjọba níwájú ọba. +“Jẹ́ kí á wá àwọn wundia tí wọ́n lẹ́wà fún ọba, kí á yan àwọn eniyan ní gbogbo ìgbèríko ìjọba rẹ̀ láti ṣa àwọn wundia tí wọ́n lẹ́wà wá sí ibi tí àwọn ayaba ń gbé ní ààfin, ní Susa, tíí ṣe olú ìlú, kí wọ́n wà lábẹ́ ìtọ́jú Hegai, ìwẹ̀fà ọba, tíí ṣe olùtọ́jú àwọn ayaba, kí á sì fún wọn ní àwọn ohun ìpara, +kí wundia tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn jù sì jẹ́ ayaba dípò Faṣiti.” Ìmọ̀ràn yìí dùn mọ́ ọba ninu, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. +Ọkunrin kan, ará Juda láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini wà ní ààfin Susa, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Modekai, ọmọ Jairi, ọmọ Ṣimei, ọmọ Kiṣi. +Ó wà lára àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lẹ́rú láti Jerusalẹmu lọ sí ilẹ̀ Babiloni pẹlu Jekonaya, ọba Juda. +Modekai ń tọ́ ọmọbinrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hadasa tabi Ẹsita. Ọmọ yìí jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ṣugbọn kò ní òbí mọ́. Ọmọ náà lẹ́wà gidigidi. Modekai mú un sọ́dọ̀ bí ọmọ ara rẹ̀, lẹ́yìn tí baba ati ìyá rẹ̀ ti kú. +Nígbà tí ọba pàṣẹ, tí wọ́n kéde rẹ̀, tí wọ́n sì mú ọpọlọpọ wundia wá sí ààfin, ní Susa, ní abẹ́ ìtọ́jú Hegai, tí ń tọ́jú àwọn ayaba, Ẹsita wà pẹlu wọn ní ààfin ní abẹ́ ìtọ́jú rẹ̀. +Ẹsita wú Hegai lórí, inú rẹ̀ dùn sí i pupọ. Ó fún un ní nǹkan ìpara ati oúnjẹ kíákíá. Ó tún fún un ní àwọn ọmọbinrin meje ninu àwọn iranṣẹbinrin tí wọ́n wà ní ààfin. Ó fún Ẹsita ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ní ibi tí ó dára jùlọ ní ibi tí àwọn ayaba ń gbé. +Ẹsita Di Ayaba. +Ahasu-erusi ọba gbé Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, ga ju gbogbo àwọn ìjòyè yòókù lọ. +Ọba bọ́ òrùka àṣẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó fún Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Juu. +Ọba sọ fún un pé, “Má wulẹ̀ san owó kankan, àwọn eniyan náà wà ní ìkáwọ́ rẹ, lọ ṣe wọ́n bí o bá ti fẹ́.” +Ní ọjọ́ kẹtala, oṣù kinni, Hamani pe àwọn akọ̀wé ọba jọ, wọ́n sì kọ gbogbo àṣẹ tí Hamani pa sinu ìwé. Wọ́n fi ìwé náà ranṣẹ sí àwọn gomina agbègbè ati àwọn olórí àwọn eniyan ati sí àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ati ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn. Wọ́n kọ ìwé náà ní orúkọ ọba, wọ́n sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì rẹ̀. +Wọ́n fi àwọn ìwé náà rán àwọn òjíṣẹ́ sí gbogbo agbègbè ọba pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Juu run, ati kékeré ati àgbà, ati obinrin ati ọmọde ní ọjọ́ kan náà, tíí ṣe ọjọ́ kẹtala oṣù kejila oṣù Adari, kí wọ́n sì kó gbogbo ohun ìní wọn. +Wọ́n níláti sọ ohun tí ó wà ninu ìwé náà di òfin ní gbogbo ìgbèríko, kí wọ́n sì sọ fún gbogbo eniyan, kí wọ́n lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ náà. +Wọ́n pa àṣẹ náà ní Susa tíí ṣe olú-ìlú, àwọn òjíṣẹ́ sì yára mú un lọ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba. Lẹ́yìn náà, Hamani ati ọba jókòó láti mu ọtí, ṣugbọn gbogbo ìlú Susa wà ninu ìdààmú. +Gbogbo àwọn olóyè ní ẹnu ọ̀nà ààfin ọba a sì máa foríbalẹ̀ láti bu ọlá fún Hamani, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, ṣugbọn Modekai kò jẹ́ foríbalẹ̀ kí ó bu ọlá fún Hamani. +Àwọn olóyè kan ninu wọn bi Modekai léèrè pé, “Kí ló dé tí o fi ń tàpá sí àṣẹ ọba?” +Ojoojumọ ni wọ́n ń kìlọ̀ fún un, ṣugbọn kò gbọ́. Nítorí náà, wọ́n lọ sọ fún Hamani, wọ́n fẹ́ mọ̀ bóyá ohun tí Modekai sọ ni yóo ṣẹ, nítorí ó sọ fún wọn pé Juu ni òun. +Nígbà tí Hamani rí i pé Modekai kọ̀, kò foríbalẹ̀ fún òun, inú bí i pupọ. +Nígbà tí ó mọ̀ pé Juu ni, ó kà á sí ohun kékeré láti pa Modekai nìkan, nítorí náà, ó pinnu láti pa gbogbo àwọn Juu tí wọ́n jẹ́ eniyan Modekai run, ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi. +Ní ọdún kejila ìjọba Ahasu-erusi, Hamani pinnu láti yan ọjọ́ tí ó wọ̀, nítorí náà, ní oṣù kinni tíí ṣe oṣù Nisani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́ gègé tí wọn ń pè ní Purimu, níwájú Hamani láti ọjọ́ dé ọjọ́ ati láti oṣù dé oṣù, títí dé oṣù kejila tíí ṣe oṣù Adari. +Nígbà náà ni Hamani lọ bá Ahasu-erusi ọba, ó sọ fún un pé, “Àwọn eniyan kan wà tí wọ́n fọ́n káàkiri ààrin àwọn eniyan ati ní gbogbo agbègbè ìjọba rẹ; òfin wọn kò bá ti gbogbo eniyan mu, wọn kò sì pa àṣẹ ọba mọ́. Kò dára kí o gbà wọ́n láàyè ninu ìjọba rẹ. +Bí ó bá dùn mọ́ Kabiyesi ninu, jẹ́ kí àṣẹ kan jáde lọ láti pa wọ́n run. N óo sì gbé ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka fún àwọn tí a bá fi iṣẹ́ náà rán, kí wọ́n gbé e sí ilé ìṣúra ọba.” +Hamani Dìtẹ̀ láti Pa Àwọn Juu Run. +Nígbà tí Modekai gbọ́ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Ó fi àkísà ati eérú bo ara rẹ̀. Ó kígbe lọ sí ààrin ìlú, ó ń pohùnréré ẹkún. +Ẹsita tún rán an pada sí Modekai pé, +“Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ati gbogbo eniyan ni wọ́n mọ̀ pé bí ẹnikẹ́ni bá lọ sọ́dọ̀ ọba ninu yàrá inú lọ́hùn-ún, láìṣe pé ọba pè é, òfin kan tí ọba ní fún irú eniyan bẹ́ẹ̀ ni pé kí á pa á, àfi bí ọba bá na ọ̀pá wúrà tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni náà ni wọn kò fi ní pa á. Ṣugbọn ó ti tó ọgbọ̀n ọjọ́ sẹ́yìn tí ọba ti pè mí.” +Nígbà tí Modekai gbọ́ ìdáhùn yìí láti ọ̀dọ̀ Ẹsita, +ó tún ranṣẹ sí Ẹsita pada, ó ní, “Má rò pé ìwọ nìkan óo là láàrin àwọn Juu, nítorí pé o wà ní ààfin ọba. +Bí o bá dákẹ́ ní irú àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́, ati ìgbàlà yóo ti ibòmíràn wá fún àwọn Juu, ṣugbọn a óo pa ìwọ ati àwọn ará ilé baba rẹ run. Ta ni ó sì lè sọ, bóyá nítorí irú àkókò yìí ni o fi di ayaba?” +Ẹsita bá ranṣẹ sí Modekai, ó ní, +“Lọ kó gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa jọ, kí ẹ gba ààwẹ̀ fún mi fún ọjọ́ mẹta, láìjẹ, láìmu, láàárọ̀ ati lálẹ́. Èmi ati àwọn iranṣẹ mi náà yóo máa gbààwẹ̀ níhìn-ín. Lẹ́yìn náà, n óo lọ rí ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin, bí n óo bá kú, kí n kú.” +Modekai bá lọ, ó ṣe bí Ẹsita ti pàṣẹ fún un. +Ó lọ sí ẹnu ọ̀nà ààfin, ṣugbọn kò wọlé nítorí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wọ àkísà wọ inú ààfin. +Ní gbogbo agbègbè ati káàkiri ibi tí òfin ati àṣẹ ọba dé, ni àwọn Juu tí ń ṣọ̀fọ̀ tí wọn ń gbààwẹ̀ tẹkúntẹkún. Ọpọlọpọ wọn da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, wọ́n sì da eérú sára. +Nígbà tí àwọn iranṣẹbinrin Ẹsita ati àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ sọ fún un nípa Modekai, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó kó aṣọ ranṣẹ sí i, kí ó lè pààrọ̀ àkísà rẹ̀, ṣugbọn Modekai kọ̀ wọ́n. +Ẹsita bá pe Hataki, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, tí ọba ti yàn láti máa ṣe iranṣẹ fún un. Ó pàṣẹ fún un pé kí ó lọ bá Modekai kí ó bèèrè ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ati ohun tí ó fà á. +Hataki lọ bá Modekai ní ìta gbangba, níwájú ẹnu ọ̀nà ààfin ọba. +Modekai sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un, títí kan iye owó tí Hamani ti pinnu láti gbé kalẹ̀ sí ilé ìṣúra ọba kí wọ́n fi pa àwọn Juu run. +Modekai fún Hataki ní ìwé òfin tí wọ́n ṣe ní Susa láti pa gbogbo àwọn Juu run patapata, pé kí ó fi ìwé náà han Ẹsita, kí ó sì là á yé e, kí ó lè lọ siwaju ọba láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀. +Hataki pada lọ ròyìn ohun tí Modekai sọ fún Ẹsita. +Modekai Wá Ìrànlọ́wọ́ Ẹsita. +Ní ọjọ́ kẹta, Ẹsita wọ aṣọ oyè rẹ̀, ó dúró ní àgbàlá ààfin ọba, ó kọjú sí gbọ̀ngàn ọba. Ọba jókòó lórí ìtẹ́ ninu gbọ̀ngàn rẹ̀, ó kọjú sí ẹnu ọ̀nà. +Ṣugbọn Hamani pa á mọ́ra, ó lọ sí ilé rẹ̀. Ó pe gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati iyawo rẹ̀ tí ń jẹ́ Sereṣi, +ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu fún wọn bí ọrọ̀ rẹ̀ ti pọ̀ tó, iye àwọn ọmọ rẹ̀, bí ọba ṣe gbé e ga ju gbogbo àwọn ìjòyè ati àwọn olórí yòókù lọ. +Hamani tún fi kún un pé “Ayaba Ẹsita kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni bá ọba wá sí ibi àsè rẹ̀, àfi èmi nìkan. Ó sì ti tún pe èmi ati ọba sí àsè mìíràn ní ọ̀la. +Ṣugbọn gbogbo nǹkan wọnyi kò lè tẹ́ mi lọ́rùn, bí mo bá ń rí Modekai, Juu, tí ó ń jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin ọba.” +Sereṣi iyawo rẹ̀ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un, pé, “Lọ ri igi tí wọn ń gbé eniyan kọ́, kí ó ga ní ìwọ̀n aadọta igbọnwọ. Bí ilẹ̀ bá ti mọ́, sọ fún ọba pé kí ó so Modekai kọ́ sí orí igi náà. Nígbà náà inú rẹ yóo dùn láti lọ sí ibi àsè náà.” Inú Hamani dùn sí ìmọ̀ràn yìí, ó lọ ri igi náà mọ́lẹ̀. +Nígbà tí ó rí Ẹsita tí ó dúró ní ìta, inú rẹ̀ dùn sí i, ọba na ọ̀pá oyè tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ sí i, Ẹsita sì na ọwọ́, ó fi kan ṣóńṣó ọ̀pá náà. +Ọba bi ayaba Ẹsita pé, “Ẹsita, kí ló dé? Kí ni ẹ̀dùn ọkàn rẹ? A óo fún ọ, títí dé ìdajì ìjọba mi.” +Ẹsita bá dáhùn pé, “Bí inú kabiyesi bá dùn sí mi, mo fẹ́ kí kabiyesi ati Hamani wá sí ibi àsè tí n óo sè fun yín ní alẹ́ òní.” +Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ lọ pe Hamani wá kíákíá, kí á lè lọ ṣe ohun tí Ẹsita bèèrè.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati Hamani ṣe lọ sí ibi àsè tí Ẹsita ti sè sílẹ̀. +Bí wọn tí ń mu ọtí, ọba tún bi Ẹsita léèrè pé, “Kí ni ìbéèrè rẹ Ẹsita, a óo ṣe é fún ọ, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ ni a óo jẹ́ kí ó tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ títí dé ìdajì ìjọba mi.” +Ẹsita bá dáhùn pé, “Ìbéèrè ati ẹ̀bẹ̀ mi ni pé, +bí inú kabiyesi bá dùn sí mi láti ṣe ohun tí mò ń fẹ́, ati láti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, kí kabiyesi ati Hamani wá síbi àsè tí n óo sè fún wọn ní ọ̀la. Nígbà náà ni n óo sọ ohun tí ó wà ní ọkàn mi.” +Hamani jáde pẹlu ayọ̀ ńlá, ati ìdùnnú. Ṣugbọn nígbà tí ó rí Modekai ní ẹnu ọ̀nà ààfin, tí kò tilẹ̀ mira rárá tabi kí ó wárìrì, inú bí i sí Modekai. +Ẹsita Pe Ọba ati Hamani sí Àsè. +Ní òru ọjọ́ náà, ọba kò lè sùn. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n gbé ìwé àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìjọba rẹ̀ wá, kí wọ́n sì kà á sí etígbọ̀ọ́ òun. +Ọba bá sọ fún Hamani pé, “Yára lọ mú aṣọ ìgúnwà, ati ẹṣin náà, kí o sì ṣe bí o ti wí sí Modekai, Juu, tí ó máa ń jókòó sí ẹnu ọ̀nà ààfin.” +Hamani lọ mú ẹ̀wù ati ẹṣin náà, ó ṣe Modekai lọ́ṣọ̀ọ́, ó gbé e gun ẹṣin, ó sì ń ké níwájú rẹ̀ bí ó ti ń fà á káàkiri gbogbo ìlú pé, “Ẹ wo ohun tí ọba ṣe fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí láti dá lọ́lá.” +Lẹ́yìn náà, Modekai pada sí ẹnu ọ̀nà ààfin, ṣugbọn Hamani sáré pada lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́, ó sì bo orí rẹ̀. +Ó sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi, iyawo rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ ati iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí Modekai, ẹni tí o ti bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀ níwájú rẹ̀ bá jẹ́ Juu, o kò ní lè ṣẹgun rẹ̀, òun ni yóo ṣẹgun rẹ.” +Bí wọ́n ti ń bá Hamani sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni àwọn ìwẹ̀fà ọba dé láti yára mú un lọ sí ibi àsè Ẹsita. +Wọ́n kà á ninu àkọsílẹ̀ pé Modekai tú àṣírí Bigitana ati Tereṣi, àwọn ìwẹ̀fà meji tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọba, tí wọ́n dìtẹ̀ láti pa Ahasu-erusi ọba. +Ọba bèèrè pé irú ọlá wo ni a dá Modekai fún ohun tí ó ṣe yìí? Wọ́n dá a lóhùn pé ẹnikẹ́ni kò ṣe nǹkankan fún un. +Ọba bèèrè pé, “Ta ló wà ninu àgbàlá?” Àkókò náà ni Hamani wọ inú àgbàlá ààfin ọba, láti bá ọba sọ̀rọ̀ láti so Modekai rọ̀ sórí igi tí ó rì mọ́lẹ̀. +Àwọn iranṣẹ ọba dá a lóhùn pé, “Hamani wà níbẹ̀ tí ó ń duro ní àgbàlá.” Ọba sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí ó wọlé.” +Bí Hamani tí ń wọlé ni ọba bi í pé, “Kí ló yẹ kí á ṣe fún ẹni tí inú ọba dùn sí?”Hamani rò ó ninu ara rẹ̀ pé, ta ni ọba ìbá tún dá lọ́lá bíkòṣe òun. +Nítorí náà, ó dá ọba lóhùn pé, “Báyìí ni ó ṣe yẹ kí á dá ẹni tí inú ọba dùn sí lọ́lá: +kí wọ́n mú aṣọ ìgúnwà ọba, tí ọba ti wọ̀ rí, ati ẹṣin tí ó ti gùn rí, kí wọ́n sì fi adé ọba dé ẹni náà lórí, +kí wọ́n kó wọn fún ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ, kí ó fi ṣe ẹni náà lọ́ṣọ̀ọ́, kí ó gbé e gun ẹṣin, kí ó sì fà á káàkiri gbogbo ìlú, kí ó máa kéde pé, ‘Ẹ wo ohun tí ọba ṣe fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí láti dá a lọ́lá.’ ” +Ọba Dá Modekai Lọ́lá. +Ọba ati Hamani lọ bá Ayaba Ẹsita jẹ àsè. +Ọba bá ní kí wọ́n lọ gbé Hamani kọ́ sí orí rẹ̀. Wọ́n bá gbé Hamani kọ́ sí orí igi tí ó ti rì mọ́lẹ̀ fún Modekai, nígbà náà ni inú ọba tó rọ̀. +Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń mu ��tí, ọba tún bi Ẹsita pé, “Ẹsita, Ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ, a óo ṣe é fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ, gbogbo rẹ̀ ni yóo sì tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́, àní títí kan ìdajì ìjọba mi.” +Ẹsita ayaba dáhùn, ó ní, “Kabiyesi, bí mo bá rí ojurere rẹ, bí ó bá sì wù ọ́, dá ẹ̀mí mi ati ti àwọn eniyan mi sí. +Wọ́n ti ta èmi ati àwọn eniyan mi fún pípa, wọn ó sì pa wá run. Bí ó bá jẹ́ pé wọ́n ta tọkunrin tobinrin wa bí ẹrú lásán ni, n kì bá tí yọ ìwọ kabiyesi lẹ́nu rárá, nítorí a kò lè fi ìnira wa wé àdánù tí yóo jẹ́ ti ìwọ ọba.” +Ahasu-erusi ọba bi Ẹsita Ayaba pé, “Ta ni olúwarẹ̀, níbo ni ẹni náà wà, tí ń gbèrò láti dán irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wò?” +Ẹsita bá dá a lóhùn pé, “Ọlọ̀tẹ̀ ati ọ̀tá náà ni Hamani eniyan burúkú yìí.” Ẹ̀rù ba Hamani gidigidi níwájú ọba ati ayaba. +Ọba dìde kúrò ní ibi àsè náà pẹlu ibinu, ó jáde lọ sinu àgbàlá ààfin. Nígbà tí Hamani rí i pé ọba ti pinnu ibi fún òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Ẹsita Ayaba fún ẹ̀mí rẹ̀. +Bí ọba ti pada wá láti inú àgbàlá sí ibi tí wọ́n ti ń mu ọtí, ó rí Hamani tí ó ṣubú sí ibi àga tí Ẹsita rọ̀gbọ̀kú sí. Ọba ní, “Ṣé yóo tún máa fi ọwọ́ pa Ayaba lára lójú mi ni, ninu ilé mi?” Ní kété tí ọba sọ̀rọ̀ yìí tán, wọ́n faṣọ bo Hamani lójú. +Habona, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, bá sọ fún ọba pé, “Igi kan, tí ó ga ní aadọta igbọnwọ (mita 22) wà ní ilé rẹ̀, tí ó ti rì mọ́lẹ̀ láti gbé Modekai kọ́ sí, Modekai tí ó gba ẹ̀mí rẹ là.” +Ní ọjọ́ náà gan-an ni ọba Ahasu-erusi fún Ẹsita Ayaba ní ilé Hamani, ọ̀tá àwọn Juu. Ẹsita wá sọ fún ọba pé eniyan òun ni Modekai. Láti ìgbà náà ni ọba sì ti mú Modekai wá siwaju rẹ̀. +Wọ́n kọ ìwé náà ní orúkọ Ahasu-erusi ọba, wọ́n sì fi òrùka ọba tẹ̀ ẹ́ bí èdìdì. Wọ́n fi rán àwọn iranṣẹ tí wọn ń gun àwọn ẹṣin tí wọ́n lè sáré dáradára, àwọn ẹṣin tí wọn ń lò fún iṣẹ́ ọba, àwọn tí wọ́n ń bọ́ fún ìlò ọba. +Òfin náà fún àwọn Juu ní àṣẹ láti kó ara wọn jọ, láti gba ara wọn sílẹ̀, ati láti run orílẹ̀-èdè tabi ìgbèríko tí ó bá dojú ìjà kọ wọ́n, ati àwọn ọmọ wọn, ati àwọn obinrin wọn. Wọ́n lè run ọ̀tá wọn láì ku ẹnìkan, kí wọ́n sì gba gbogbo ìní wọn. +Àṣẹ yìí gbọdọ̀ múlẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Pasia, ní ọjọ́ tí wọ́n yàn láti pa gbogbo àwọn Juu, ní ọjọ́ kẹtala oṣù kejila, tíí ṣe oṣù Adari. +Àkọsílẹ̀ yìí di òfin fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèríko, kí àwọn Juu baà lè múra láti gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn ní ọjọ́ náà. +Pẹlu àṣẹ ọba, àwọn iranṣẹ gun àwọn ẹṣin ọba, wọ́n sì yára lọ. Wọ́n pa àṣẹ náà ní Susa tíí ṣe olú-ìlú. +Modekai jáde ní ààfin ninu aṣọ ọba aláwọ̀ aró ati funfun pẹlu adé wúrà ńlá. Ó wọ aṣọ ìlékè aláwọ̀ elése-àlùkò, ìlú Susa sì ń hó fún ayọ̀. +Àwọn Juu sì ní ìmọ́lẹ̀ ati inú dídùn, ayọ̀ ati ọlá. +Ní gbogbo agbègbè, ati ní àwọn ìlú tí ìkéde yìí dé, ìdùnnú ati ayọ̀ kún inú àwọn Juu, wọ́n se àsè pẹlu ayẹyẹ, wọ́n sì gba ìsinmi. Àwọn ẹ̀yà mìíràn sọ ara wọn di Juu, nítorí pé ẹ̀rù àwọn Juu ń bà wọ́n. +Ọba mú òrùka tí ó gbà lọ́wọ́ Hamani, ó fi bọ Modekai lọ́wọ́. Ẹsita sì fi Modekai ṣe olórí ilé Hamani. +Ẹsita tún bẹ ọba, ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pẹlu omijé, pé kí ọba yí ète burúkú tí Hamani, ará Agagi, pa láti run àwọn Juu pada. +Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá àṣẹ wúrà sí Ẹsita. +Ó dìde, ó sì dúró níwájú ọba, ó ní, “Bí inú kabiyesi bá dùn sí mi, tí mo sì rí ojurere rẹ̀, bí ó bá fẹ́ràn mi, tí ọ̀rọ̀ náà bá tọ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí ìwé àṣẹ kan ti ọ̀dọ̀ ọba jáde, láti yí ète burúkú tí Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, pa pada, àní ète tí ó pa láti run gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà ní ìjọba rẹ̀. +Mo ṣe lè rí jamba tí ń bọ̀, tabi ìparun tí ń bọ̀ sórí àwọn eniyan mi, kí n sì dákẹ́?” +Ahasu-erusi ọba dá Ẹsita Ayaba ati Modekai Juu lóhùn pé, “Mo ti so Hamani kọ́ sórí igi, nítorí ète tí ó pa lórí àwọn Juu, mo sì ti fún Ẹsita ní ilé rẹ̀. +Kọ ohunkohun tí ó bá wù ọ́ nípa àwọn Juu ní orúkọ ọba, kí o sì fi òrùka ọba tẹ̀ ẹ́ bí èdìdì. Nítorí pé òfin tí a bá kọ ní orúkọ ọba, tí ó sì ní èdìdì ọba, ẹnikẹ́ni kò lè yí i pada mọ́.” +Ọjọ́ kẹtalelogun oṣù kẹta, tíí ṣe oṣù Sifani ni Modekai pe àwọn akọ̀wé ọba, wọ́n sì kọ òfin sílẹ̀ nípa àwọn Juu g��̣gẹ́ bí Modekai ti sọ fún wọn. Wọ́n fi ranṣẹ sí àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn gomina, ati àwọn olórí àwọn agbègbè, láti India títí dé Etiopia, gbogbo wọn jẹ́ agbègbè mẹtadinlaadoje (127). Wọ́n kọ ọ́ sí agbègbè kọ̀ọ̀kan ati ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, wọ́n sì kọ sí àwọn Juu náà ní èdè wọn. +Wọ́n fún Àwọn Juu Láṣẹ láti Bá Àwọn Ọ̀tá Wọn Jà. +Ní ọjọ́ kẹtala oṣù Adari tíí ṣe oṣù kejila, nígbà tí wọ́n ń múra láti ṣe ohun tí òfin ọba wí, ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá rò pé ọwọ́ wọn yóo tẹ àwọn Juu, ṣugbọn, tí ó jẹ́ ọjọ́ tí àwọn Juu ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn; +Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá jẹ́ ọmọ Hamani, ọmọ Hamedata, ọ̀tá àwọn Juu, ṣugbọn wọn kò fọwọ́ kan àwọn ẹrù wọn. +Ní ọjọ́ náà, wọ́n mú ìròyìn iye àwọn tí wọ́n pa ní Susa wá fún ọba. +Ọba sọ fún Ẹsita Ayaba pé, “Àwọn Juu ti pa ẹẹdẹgbẹta (500) ọkunrin ati àwọn ọmọ Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ní Susa. Kí ni àwọn Juu tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè ṣe? Nisinsinyii, kí ni ìbéèrè rẹ? A óo sì ṣe é fún ọ.” +Ẹsita dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, jẹ́ kí á fún àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní sí àwọn ọ̀tá wọn ní ọ̀la, kí á sì so àwọn ọmọ Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá rọ̀ sí orí igi.” +Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àṣẹ bá jáde láti Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọ Hamani rọ̀ sí orí igi. +Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa tún parapọ̀, wọ́n sì pa ọọdunrun (300) ọkunrin sí i. Ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn. +Àwọn Juu tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè kó ara wọn jọ láti gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n pa ẹgbaa mejidinlogoji ó dín ẹgbẹrun (75,000) ninu àwọn tí wọ́n kórìíra wọn, ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn. +Ní ọjọ́ kẹtala oṣù Adari ni èyí ṣẹlẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrinla, wọ́n sinmi; ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ àsè ati ayọ̀. +Ní Susa, ọjọ́ kẹẹdogun oṣù ni wọ́n tó ṣe ayẹyẹ tiwọn. Ọjọ́ kẹtala ati ọjọ́ kẹrinla ni àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa pa àwọn ọ̀tá wọn, ní ọjọ́ kẹẹdogun, wọ́n sinmi, ó sì jẹ́ ọjọ́ àsè ati ayọ̀ fún wọn. +Ìdí nìyí tí àwọn Juu tí wọn ń gbé àwọn agbègbè fi ya ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari sọ́tọ̀ fún ọjọ́ àsè, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn. +àwọn Juu péjọ ninu àwọn ìlú wọn ní àwọn ìgbèríko ilẹ̀ Ahasu-erusi ọba, wọ́n múra láti bá àwọn tí wọ́n fẹ́ pa wọ́n run jà. Kò sí ẹni tí ó lè kò wọ́n lójú nítorí pé gbogbo àwọn eniyan ni wọ́n ń bẹ̀rù wọn. +Modekai kọ gbogbo nǹkan wọnyi sílẹ̀, Ó sì fi ranṣẹ sí àwọn Juu tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi ọba, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní òkèèrè, +pé kí wọ́n ya ọjọ́ kẹrinla ati ọjọ́ kẹẹdogun oṣù Adari sọ́tọ̀, +gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí àwọn Juu gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí ìbànújẹ́ ati ẹ̀rù wọn di ayọ̀, tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn sì di ọjọ́ àjọ̀dún. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àjọ̀dún ati ayọ̀, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn, tí wọn yóo máa fún àwọn talaka ní ẹ̀bùn. +Àwọn Juu gbà láti máa ṣe bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ati bí àṣẹ Modekai. +Nítorí Hamani, ọmọ Hamedata, láti ìran Agagi, ọ̀tá àwọn Juu ti pète láti pa àwọn Juu run. Ó ti ṣẹ́ gègé, tí wọn ń pè ní Purimu, láti mọ ọjọ́ tí yóo pa àwọn Juu run patapata. +Ṣugbọn nígbà tí Ẹsita lọ sọ́dọ̀ ọba, ọba kọ̀wé àṣẹ tí ó mú kí ìpinnu burúkú tí Hamani ní sí àwọn Juu pada sí orí òun tìkararẹ̀, a sì so òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ rọ̀ sórí igi. +Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ọjọ́ náà ní Purimu gẹ́gẹ́ bí orúkọ Purimu, gègé tí Hamani ṣẹ́. Nítorí ìwé tí Modekai kọ ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, +ni àwọn Juu fi sọ ọ́ di òfin fún ara wọn, ati fún arọmọdọmọ wọn, ati fún àwọn tí wọ́n bá di Juu, pé ní àkókò rẹ̀, ní ọdọọdún, ọjọ́ mejeeji yìí gbọdọ̀ jẹ́ ọjọ́ àsè, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Modekai, +ati pé kí wọ́n máa ranti àwọn ọjọ́ wọnyi, kí wọ́n sì máa pa wọ́n mọ́ láti ìrandíran, ní gbogbo ìdílé, ní gbogbo agbègbè ati ìlú. Àwọn ọjọ́ Purimu wọnyi kò gbọdọ̀ yẹ̀ láàrin àwọn Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìrántí wọn kò gbọdọ̀ parun láàrin arọmọdọmọ wọn. +Ẹsita Ayaba, ọmọbinrin Abihaili, ati Modekai, tíí ṣe Juu kọ ìwé láti fi ìdí ìwé keji nípa Purimu múlẹ̀. +Gbogbo àwọn olórí àwọn agbègbè, àwọn baálẹ̀, àwọn gomina ati àwọn aláṣẹ ọba ran àwọn Juu lọ́wọ́, nítorí pé ẹ̀rù Modekai ń bà wọ́n. +Wọ́n kọ ìwé sí gbogbo àwọn Juu ní gbogbo agbègbè mẹtẹẹtadinlaadoje (127) tí ó wà ninu ìjọba Ahasu-erusi. Ìwé náà kún fún ọ̀rọ̀ alaafia ati òtítọ́, +pé wọn kò gbọdọ̀ gbàgbé láti máa pa àwọn ọjọ́ Purimu mọ́ ní àkókò wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Modekai ati Ẹsita Ayaba pa fún àwọn Juu, ati irú ìlànà tí wọ́n là sílẹ̀ fún ara wọn ati arọmọdọmọ wọn, nípa ààwẹ̀ ati ẹkún wọn. +Àṣẹ tí Ẹsita pa fi ìdí àjọ̀dún Purimu múlẹ̀, wọ́n sì kọ ọ́ sílẹ̀. +Modekai di eniyan pataki ní ààfin; òkìkí rẹ̀ kàn dé gbogbo agbègbè, agbára rẹ̀ sì ń pọ̀ sí i. +Àwọn Juu fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n pa wọ́n run. Ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí àwọn tí wọ́n kórìíra wọn. +Ní ìlú Susa nìkan, àwọn Juu pa ẹẹdẹgbẹta (500) eniyan. +Wọ́n sì pa Paṣandata, Dalifoni, Asipata, +Porata, Adalia, Aridata, +Pamaṣita, Arisai, Aridai ati Faisata. +Àwọn Juu Pa Àwọn Ọ̀tá Wọn Run. +Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá Jakọbu wá sí Ijipti nìwọ̀nyí, olukuluku pẹlu ìdílé rẹ̀: +Ẹ jẹ́ kí á fi ọgbọ́n bá wọn lò, nítorí bí wọ́n bá ń pọ̀ lọ báyìí, bí ogun bá bẹ́ sílẹ̀, wọn yóo darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa láti bá wa jà, wọn yóo sì sá kúrò ní ilẹ̀ yìí.” +Nítorí náà, wọ́n yan àwọn akóniṣiṣẹ́ láti ni wọ́n lára pẹlu iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n lò wọ́n láti kọ́ ìlú Pitomi ati Ramesesi tíí ṣe àwọn ìlú ìṣúra fún Farao. +Ṣugbọn bí wọ́n ti ń da àwọn ọmọ Israẹli láàmú tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, tí wọ́n sì ń tàn kálẹ̀. Ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí ba àwọn ará Ijipti. +Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi iṣẹ́ àṣekára ni àwọn ọmọ Israẹli lára, +wọ́n sì ń fòòró ẹ̀mí wọn pẹlu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ líle. Wọ́n ń po yẹ̀ẹ̀pẹ̀, wọ́n ń mọ bíríkì, wọ́n ń ṣiṣẹ́ ninu oko. Pẹlu ìnira ni wọ́n sì ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọn ń ṣe. +Nígbà tí ó yá, ọba Ijipti pe àwọn obinrin Heberu tí wọ́n ń gbẹ̀bí, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣifira ati Pua, ó sọ fún wọn pé, +“Nígbà tí ẹ bá ń gbẹ̀bí fún àwọn obinrin Israẹli, tí ẹ sì rí i pé ọmọ tí wọ́n fẹ́ bí jẹ́ ọkunrin, ẹ pa á, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ obinrin ni, ẹ dá a sí.” +Ṣugbọn àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọrun; wọn kò tẹ̀lé àṣẹ tí ọba Ijipti pa fún wọn, pé kí wọn máa pa àwọn ọmọkunrin tí àwọn obinrin Heberu bá ń bí. +Ọba Ijipti bá pe àwọn agbẹ̀bí náà, ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dá àwọn ọmọkunrin tí àwọn Heberu bí sí?” +Wọ́n dá Farao lóhùn pé, “Àwọn obinrin Heberu yàtọ̀ sí àwọn obinrin Ijipti. Wọ́n lágbára, wọn a sì ti máa bímọ kí á tó dé ọ̀dọ̀ wọn.” +Reubẹni, Simeoni, Lefi, Juda, +Nítorí náà, Ọlọrun ṣe àwọn agbẹ̀bí náà dáradára; àwọn eniyan Israẹli ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ń lágbára sí i. +Nítorí pé àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọrun, ìdílé tiwọn náà pọ̀ síi. +Farao bá pàṣẹ fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Gbogbo ọmọkunrin tí àwọn Heberu bá bí, ẹ máa gbé wọn sọ sinu odò Naili, ṣugbọn kí ẹ dá àwọn ọmọbinrin wọn sí.” +Isakari, Sebuluni, Bẹnjamini, +Dani, Nafutali, Gadi ati Aṣeri. +Gbogbo àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Jakọbu jẹ́ aadọrin, Josẹfu ti wà ní Ijipti ní tirẹ̀. +Nígbà tí ó yá, Josẹfu kú, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ náà kú ní ọ̀kọ̀ọ̀kan títí tí gbogbo ìran náà fi kú tán. +Ṣugbọn àwọn arọmọdọmọ Israẹli pọ̀ sí i, wọ́n di alágbára gidigidi, wọ́n sì pọ̀ káàkiri ní ilẹ̀ Ijipti. +Nígbà tí ó yá, ọba titun kan tí kò mọ Josẹfu gorí oyè, ní ilẹ̀ Ijipti. +Ọba yìí sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ wò bí àwọn ọmọ Israẹli wọnyi ti pọ̀ tó, tí wọ́n sì lágbára jù wá lọ. +Àwọn Ará Ijipti Fipá Kó Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣiṣẹ́. +OLUWA bá pe Mose, ó ní, “Wọlé tọ Farao lọ, nítorí pé mo tún ti mú ọkàn rẹ̀ le, ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, kí n lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrin wọn. +Farao bá dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín bí mo bá jẹ́ kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín lọ. Wò ó, ète burúkú wà ní ọkàn yín. +N ò gbà! Ẹ̀yin ọkunrin nìkan ni kí ẹ lọ sin OLUWA; nítorí pé bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ fẹ́ àbí?” Wọ́n bá lé wọn jáde kúrò níwájú Farao. +OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sórí ilẹ̀ Ijipti, kí eṣú lè tú jáde, kí wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà, kí wọ́n jẹ gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ náà tí yìnyín kò pa.” +Mose bá gbé ọ̀pá rẹ̀, ó nà án sókè, sórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti. OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ wá láti ìlà oòrùn, afẹ́fẹ́ náà fẹ́ sórí gbogbo ilẹ̀ náà, ní gbogbo ọ̀sán ati ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Nígbà tí yóo fi di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, afẹ́fẹ́ ti kó eṣú dé. +Eṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, wọ́n sì bà sí gbogbo ilẹ̀. Wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé irú rẹ̀ kò sí rí, irú rẹ̀ kò sì tún tíì ṣẹlẹ̀ mọ́ láti ìgbà náà. +Nítorí pé wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo ojú ọ̀run ṣókùnkùn dudu, wọ́n sì jẹ gbogbo ewé, ati gbogbo èso tí ń bẹ lórí igi, ati koríko tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa. Ẹyọ ewé kan kò kù lórí igi, tabi koríko, tabi ohun ọ̀gbìn kan ninu oko, jákèjádò ilẹ̀ Ijipti. +Farao bá yára pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín ati sí ẹ̀yin pàápàá. +Ẹ jọ̀wọ́, ẹ dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, ẹ bá mi bẹ OLUWA Ọlọrun yín ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré yìí, kí ó jọ̀wọ́ mú ikú yìí kúrò lọ́dọ̀ mi.” +Mose bá jáde kúrò níwájú Farao, ó lọ gbadura sí OLUWA. +OLUWA bá yí afẹ́fẹ́ líle ìwọ̀ oòrùn pada, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ àwọn eṣú náà lọ sí inú Òkun Pupa, ẹyọ eṣú kan ṣoṣo kò sì kù mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. +Kí ẹ̀yin náà sì lè sọ fún àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ yín, irú ohun tí mo fi ojú wọn rí, ati irú iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe láàrin wọn; kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +Ṣugbọn OLUWA tún mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ. +OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, kí òkùnkùn lè ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, òkùnkùn biribiri tí eniyan fẹ́rẹ̀ lè dì mú.” +Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún odidi ọjọ́ mẹta. +Wọn kò lè rí ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò sì dìde kúrò níbi tí ó wà fún ọjọ́ mẹta. Ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ wà ní gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé. +Farao bá tún ranṣẹ lọ pe Mose, ó ní, “Ẹ lọ sin Ọlọrun yín, ẹ máa kó àwọn ọmọ yín lọ pẹlu, ṣugbọn ẹ fi agbo aguntan yín ati agbo ẹran yín sílẹ̀.” +Mose dáhùn pé, “O níláti jẹ́ kí á kó ẹran tí a óo fi rúbọ lọ́wọ́, ati èyí tí a óo fi rúbọ sísun sí OLUWA Ọlọrun wa. +A níláti kó àwọn ẹran ọ̀sìn wa lọ, a kò ní fi ohunkohun sílẹ̀ lẹ́yìn, nítorí pé ninu wọn ni a óo ti mú láti fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa; a kò sì tíì mọ ohun tí a óo fi rúbọ, àfi ìgbà tí a bá débẹ̀.” +Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí wọ́n lọ. +Farao bá lé Mose, ó ní, “Kúrò lọ́dọ̀ mi; kí o sì ṣọ́ra rẹ gidigidi, n kò gbọdọ̀ tún rí ọ níwájú mi mọ́; ní ọjọ́ tí mo bá tún fi ojú kàn ọ́, ọjọ́ náà ni o óo kú!” +Mose bá dáhùn, ó ní, “Bí o ti wí gan-an ni yóo rí. N kò ní dé iwájú rẹ mọ́.” +Nítorí náà, Mose ati Aaroni lọ, wọ́n sì wí fún Farao pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu ní kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé, yóo ti pẹ́ tó tí o óo fi kọ̀ láti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú òun Ọlọrun? Ó ní, kí o jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ kí wọ́n lè sin òun. +Nítorí pé bí o bá kọ̀, tí o kò jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ, ó ní òun yóo mú kí eṣú wọ ilẹ̀ rẹ lọ́la. +Àwọn eṣú náà yóo sì bo gbogbo ilẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní rí ilẹ̀ rárá, wọn yóo sì jẹ gbogbo ohun tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa, wọn yóo jẹ gbogbo igi rẹ tí ó wà ninu pápá oko. +Wọn yóo rọ́ kún gbogbo ààfin rẹ ati ilé gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ ati ilé gbogbo àwọn ará Ijipti, àwọn eṣú náà yóo burú ju ohunkohun tí àwọn baba ati àwọn baba ńlá yín ti rí rí lọ, láti ọjọ́ tí wọ́n ti dáyé títí di òní olónìí.” Mose bá yipada kúrò níwájú Farao. +Àwọn ẹmẹ̀wà Farao sọ fún un pé, “Kabiyesi, ìgbà wo ni ọkunrin yìí yóo yọ wá lẹ́nu dà? Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ kí wọ́n lè lọ sin OLUWA Ọlọrun wọn. Àbí kò tíì hàn sí kabiyesi báyìí pé gbogbo Ijipti tí ń parun tán lọ ni?” +Wọ́n bá mú Mose ati Aaroni pada tọ Farao lọ. Farao ní kí wọ́n lọ sin OLUWA Ọlọrun wọn, ṣugbọn ó bèèrè pé àwọn wo gan-an ni yóo lọ? +Mose dáhùn pé, “Gbogbo wa ni à ń lọ, ati àgbà ati èwe; ati ọkunrin ati obinrin, ati gbogbo agbo mààlúù wa, ati gbogbo agbo ẹran wa, nítorí pé a níláti lọ ṣe àjọ̀dún kan fún OLUWA.” +Eṣú Bo Oko. +Nígbà tí ó yá, OLUWA sọ fún Mose pé, “Ó ku ìyọnu kan péré, tí n óo mú bá Farao ati ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà yóo jẹ́ kí ẹ lọ. Nígbà tí ó bá gbà kí ẹ lọ, òun fúnra rẹ̀ ni yóo tì yín jáde patapata. +Mose ati Aaroni ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí wọn ṣe níwájú Farao, ṣugbọn OLUWA sì mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. +Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí olukuluku tọ aládùúgbò rẹ̀ lọ, ati ọkunrin ati obinrin wọn, kí wọ́n lọ tọrọ nǹkan ọ̀ṣọ́ fadaka ati ti wúrà.” +OLUWA jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli bá ojurere àwọn ará Ijipti pàdé, ati pé àwọn ará Ijipti ati àwọn ẹmẹ̀wà Farao ati àwọn eniyan rẹ̀ ka Mose kún eniyan pataki. +Mose bá sọ fún Farao pé, “OLUWA ní, nígbà tí ó bá di ọ̀gànjọ́ òru, òun yóo la ilẹ̀ Ijipti kọjá, +gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni yóo sì kú. Bẹ̀rẹ̀ láti orí àkọ́bí Farao, tí ó jókòó lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí iranṣẹbinrin tí ń lọ ọkà, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn. +Ariwo ẹkún ńlá yóo sọ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ rí, tí kò sì tún ní sí irú rẹ̀ mọ́. +Ṣugbọn ajá kò tilẹ̀ ní gbó ẹnikẹ́ni tabi ẹran ọ̀sìn kan, jákèjádò ààrin àwọn ọmọ Israẹli; kí ẹ lè mọ̀ pé OLUWA fi ìyàtọ̀ sí ààrin àwọn ará Ijipti ati àwọn ọmọ Israẹli. +Gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ wọnyi yóo sì tọ̀ mí wá, wọn yóo fi orí balẹ̀ fún mi, wọn yóo wí pé kí n máa lọ, èmi ati gbogbo àwọn eniyan mi! Lẹ́yìn náà ni n óo jáde lọ.” Mose bá fi tìbínú-tìbínú jáde kúrò níwájú Farao. +Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún Mose pé, “Farao kò ní gba ọ̀rọ̀ rẹ, kí iṣẹ́ ìyanu mi baà lè di pupọ ní ilẹ̀ Ijipti.” +Mose Kéde Ikú Àwọn Àkọ́bí. +OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni ní ilẹ̀ Ijipti pé, +Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó ṣẹ́kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, bí ohunkohun bá ṣẹ́kù, ẹ dáná sun ún. +Bí ẹ ó ṣe jẹ ẹ́ nìyí: ẹ di àmùrè yín mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín, ẹ wọ bàtà yín, ẹ mú ọ̀pá yín lọ́wọ́; ìkánjú ni kí ẹ fi jẹ ẹ́, nítorí pé oúnjẹ ìrékọjá fún OLUWA ni. +“Nítorí pé, ní òru ọjọ́ náà ni n óo la gbogbo ilẹ̀ Ijipti kọjá, n óo pa gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ náà, ati ti eniyan ati ti ẹranko, n óo sì jẹ gbogbo àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti níyà. Èmi ni OLUWA. +Ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá fi kun àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn gbogbo ilé yín ni yóo jẹ́ àmì láti fi gbogbo ibi tí ẹ bá wà hàn. Nígbà tí mo bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, n óo re yín kọjá; n kò ní fi àjàkálẹ̀ àrùn ba yín jà láti pa yín run nígbà tí mo bá ń jẹ àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti níyà. +Ọjọ́ ìrántí ni ọjọ́ yìí yóo jẹ́ fún yín, ní ọdọọdún ni ẹ óo sì máa ṣe àjọ̀dún rẹ̀ fún OLUWA; àwọn arọmọdọmọ yín yóo sì máa ṣe àjọ̀dún yìí bí ìlànà, gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí títí lae. +“Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Láti ọjọ́ kinni ni kí ẹ ti mú gbogbo ìwúkàrà kúrò ninu ilé yín, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu láti ọjọ́ kinni títí di ọjọ́ keje, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́. +Ní ọjọ́ kinni ati ní ọjọ́ keje, ẹ óo péjọ pọ̀ láti jọ́sìn. Ní ọjọ́ mejeeje yìí, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ rárá, àfi oúnjẹ tí ẹ óo bá jẹ nìkan ni ẹ lè sè. +Ẹ óo máa ṣe àjọ̀dún ìrántí àjọ àìwúkàrà, nítorí ọjọ́ yìí ni ọjọ́ tí mo ko yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nítorí náà ẹ óo máa ṣe ìrántí ọjọ́ náà bí ìlànà ati ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín títí lae. +Láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni yìí títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọkanlelogun oṣù náà, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ. +Kò gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ninu ilé yín fún ọjọ́ mejeeje, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́, kì báà jẹ́ àlejò tabi onílé ní ilẹ̀ náà. +“Oṣù yìí ni yóo jẹ́ oṣù kinni ọdún fún yín. +Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó ní ìwúkàrà ninu; ninu gbogbo ilé yín patapata, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ.” +Mose bá pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣa ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan ní ìdílé yín kọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì pa á fún ìrékọjá. +Ẹ mú ìdì ewé hisopu, kí ẹ tì í bọ ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá gbè sinu àwo kòtò kan, kí ẹ fi ẹ̀jẹ̀ náà kun àtẹ́rígbà ati òpó ìlẹ̀kùn mejeeji. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò sì gbọdọ̀ jáde ninu ilé títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. +Nítorí pé, OLUWA yóo rékọjá, yóo sì pa àwọn ará Ijipti. Ṣugbọn nígbà tí ó bá rí ẹ̀jẹ̀ lára àtẹ́rígbà ati lára òpó ẹnu ọ̀nà mejeeji, OLUWA yóo ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kò sì ní jẹ́ kí apanirun wọ ilé yín láti pa yín. +Ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín, ẹ gbọdọ̀ máa pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin títí lae. +Nígbà tí ẹ bá sì dé ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ìsìn yìí. +Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá sì bi yín léèrè pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ ìsìn yìí?’ +ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹbọ ìrékọjá OLUWA ni, nítorí pé ó ré ilé àwọn eniyan Israẹli kọjá ní Ijipti, nígbà tí ó ń pa àwọn ará Ijipti, ṣugbọn ó dá àwọn ilé wa sí.’ ” Àwọn eniyan Israẹli wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. +Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose ati Aaroni. +Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, OLUWA lu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ijipti pa, ó bẹ̀rẹ̀ láti orí àrẹ̀mọ ọba Farao tí ó wà lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí ẹrú tí ó wà ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn. +Ẹ sọ fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli pé, ní ọjọ́ kẹwaa oṣù yìí, ọkunrin kọ̀ọ̀kan ninu ìdílé kọ̀ọ̀kan yóo mú ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan tabi àwọ́nsìn kọ̀ọ̀kan; ọ̀dọ́ aguntan kan fún ilé kan. +Farao bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, òun ati gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Ijipti. Igbe ẹkún ńlá sì sọ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé kò sí ẹyọ ilé kan tí eniyan kò ti kú. +Farao bá ranṣẹ pe Mose ati Aaroni ní òru ọjọ́ náà, ó ní, “Ẹ gbéra, ẹ máa lọ, ẹ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan mi, ati ẹ̀yin ati àwọn eniyan Israẹli, ẹ lọ sin OLUWA yín bí ẹ ti wí. +Ẹ máa kó àwọn agbo mààlúù yín lọ, ati agbo aguntan yín, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti wí. Ẹ máa lọ; ṣugbọn ẹ súre fún èmi náà!” +Àwọn ará Ijipti bá ń kán àwọn eniyan náà lójú láti tètè máa lọ. Wọ́n ní bí wọn kò bá tètè lọ, gbogbo àwọn ni àwọn yóo di òkú. +Àwọn eniyan náà bá mú àkàrà tí wọ́n ti pò, ṣugbọn tí wọn kò tíì fi ìwúkàrà sí, wọ́n sì fi aṣọ so ọpọ́n ìpòkàrà wọn, wọ́n gbé e kọ́ èjìká. +Àwọn eniyan náà ṣe bí Mose ti sọ fún wọn, olukuluku wọn ti tọ àwọn ará Ijipti lọ, wọ́n ti tọrọ ohun ọ̀ṣọ́ fadaka ati ti wúrà ati aṣọ. +OLUWA sì jẹ́ kí wọ́n bá ojurere àwọn ará Ijipti pàdé, gbogbo ohun tí wọ́n tọrọ pátá ni àwọn ará Ijipti fún wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan Israẹli ṣe, tí wọ́n sì fi kó ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ará Ijipti lọ. +Àwọn eniyan Israẹli gbéra, wọ́n rìn láti Ramesesi lọ sí Sukotu. Iye àwọn eniyan náà tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ọkunrin, láìka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde. +Ọpọlọpọ àwọn mìíràn ni wọ́n bá wọn lọ, pẹlu ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo aguntan ati agbo mààlúù. +Wọ́n mú ìyẹ̀fun tí wọ́n ti pò ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n fi ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, nítorí pé lílé ni àwọn ará Ijipti lé wọn jáde, wọn kò sì lè dúró mú oúnjẹ mìíràn lọ́wọ́. +Bí ìdílé kan bá wà tí ó kéré jù láti jẹ ẹran ọ̀dọ́ aguntan kan tán, ìdílé yìí yóo darapọ̀ mọ́ ìdílé mìíràn ní àdúgbò rẹ̀, wọn yóo sì pín ẹran tí wọ́n bá pa gẹ́gẹ́ bí iye eniyan tí ó wà ninu ìdílé mejeeji, iye eniyan tí ó bá lè jẹ àgbò kan tán ni yóo darapọ̀ láti pín ọ̀dọ́ aguntan náà. +Àkókò tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ní ilẹ̀ Ijipti jẹ́ irinwo ọdún ó lé ọgbọ̀n (430). +Ọjọ́ tí ó pé irinwo ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) gééré, tí wọ́n ti dé ilẹ̀ Ijipti; ni àwọn eniyan OLUWA jáde kúrò níbẹ̀. +Ṣíṣọ́ ni OLUWA ń ṣọ́ wọn ní gbogbo òru ọjọ́ náà títí ó fi kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Àwọn eniyan Israẹli ya alẹ́ ọjọ́ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, láti ìrandíran wọn. Ní ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣọ́nà ní òru ní ìrántí òru àyájọ́ ọjọ́ náà. +OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Òfin àjọ ìrékọjá nìwọ̀nyí: àlejò kankan kò gbọdọ̀ ba yín jẹ oúnjẹ àjọ ìrékọjá. +Ṣugbọn àwọn ẹrú tí ẹ fi owó rà, tí ẹ sì kọ ní ilà abẹ́ lè bá yín jẹ ẹ́. +Àlejò kankan tabi alágbàṣe kò gbọdọ̀ ba yín jẹ ẹ́. +Ilé tí ẹ bá ti se oúnjẹ yìí ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ gbogbo rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ mú ninu ẹran rẹ̀ jáde, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ egungun rẹ̀. +Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó gbọdọ̀ ṣe ìrántí ọjọ́ yìí. +Bí àlejò kan bá wọ̀ sí ilé yín, tí ó bá sì fẹ́ bá yín ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá, ó gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé rẹ̀ ní ilà abẹ́, lẹ́yìn náà, ó lè ba yín ṣe àjọ̀dún náà, òun náà yóo dàbí olùgbé ilẹ̀ náà, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí kò bá kọ ilà abẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ ninu àjọ ìrékọjá náà. +Ati ẹ̀yin, ati àlejò tí ń gbé ààrin yín, òfin kan ṣoṣo ni ó de gbogbo yín.” +Ọ̀dọ́ aguntan tabi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà kò gbọdọ̀ lábàwọ́n, ó lè jẹ́ àgbò tabi òbúkọ ọlọ́dún kan. +Gbogbo àwọn eniyan Israẹli bá ṣe bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose ati Aaroni. +Ní ọjọ́ yìí gan-an ni OLUWA mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. +Wọ́n óo so ẹran wọn mọ́lẹ̀ títí di ọjọ́ kẹrinla oṣù yìí. Nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli yóo pa ẹran wọn. +Wọn yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóo fi kun àtẹ́rígbà ati ara òpó ìlẹ̀kùn mejeeji ilé tí wọn yóo ti jẹ ẹran náà. +Alẹ́ ọjọ́ náà ni kí wọ́n sun ẹran náà, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati ewébẹ̀ tí ó korò bí ewúro. +Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu ẹran yìí ní tútù, tabi bíbọ̀; sísun ni kí ẹ sun ún; ati orí rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ati àwọn nǹkan inú rẹ̀. +Àjọ Ìrékọjá. +OLUWA sọ fún Mose pé, +Nítorí náà, ẹ máa ṣe ìrántí ìlànà yìí ní àkókò rẹ̀ ní ọdọọdún. +“Nígbà tí OLUWA bá mu yín dé ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ẹ̀yin ati àwọn baba yín, tí ó bá sì fún yín ní ilẹ̀ náà, +gbogbo ohun tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí ni ẹ gbọdọ̀ yà sọ́tọ̀ fún OLUWA. Gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn yín tí ó bá jẹ́ akọ, ti OLUWA ni. +Ẹ gbọdọ̀ fi ọ̀dọ́ aguntan ra gbogbo àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín pada, bí ẹ kò bá sì fẹ́ rà wọ́n pada, dandan ni pé kí ẹ lọ́ wọn lọ́rùn pa. Ẹ gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí yín tí wọ́n jẹ́ ọkunrin pada. +Ní ọjọ́ iwájú bí àwọn ọmọkunrin yín bá bèèrè ìtumọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe lọ́wọ́ yín, ohun tí ẹ óo wí fún wọn ni pé, ‘Pẹlu ipá ni OLUWA fi mú wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí a ti wà ní ìgbèkùn rí. +Nítorí pé nígbà tí Farao ṣe orí kunkun, tí ó sì kọ̀, tí kò jẹ́ kí á lọ, OLUWA pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ijipti, ti eniyan ati ti ẹranko. Ìdí nìyí tí mo fi ń fi àkọ́bí ẹran ọ̀sìn mi, tí ó bá jẹ́ akọ rúbọ sí OLUWA, tí mo sì fi ń ra àwọn àkọ́bí mi ọkunrin pada.’ +Ẹ fi ṣe àmì sí ọwọ́ yín, ati ìgbàjú sí iwájú yín, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú wa jáde ní ilẹ̀ Ijipti.” +Nígbà tí Farao gbà pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa lọ, Ọlọrun kò mú wọn gba ọ̀nà ilẹ̀ àwọn ará Filistia, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà ibẹ̀ yá, nítorí pé Ọlọrun rò ó ninu ara rẹ̀ pé, “Kí àwọn eniyan yìí má lọ yí ọkàn pada, bí àwọn kan bá gbógun tì wọ́n lójú ọ̀nà, kí wọ́n sì sá pada sí ilẹ̀ Ijipti.” +Ṣugbọn Ọlọrun mú kí wọ́n gba ọ̀nà aṣálẹ̀, ní agbègbè Òkun Pupa, àwọn eniyan Israẹli sì jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu ìmúrasílẹ̀ ogun. +Mose kó egungun Josẹfu lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń lọ, nítorí pé Josẹfu ti mú kí àwọn ọmọ Israẹli jẹ́jẹ̀ẹ́, ó ní, “Ọlọrun yóo gbà yín là, nígbà tí ó bá yá tí ẹ̀ bá ń lọ, ẹ kó egungun mi lọ́wọ́ lọ.” +“Ya gbogbo àwọn àkọ́bí sí mímọ́ fún mi, ohunkohun tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn eniyan Israẹli, kì báà ṣe ti eniyan, tabi ti ẹranko, tèmi ni wọ́n.” +Wọ́n gbéra láti Sukotu, wọ́n pàgọ́ sí Etamu létí aṣálẹ̀. +OLUWA sì ń lọ níwájú wọn ní ọ̀sán ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu láti máa fi ọ̀nà hàn wọ́n, ati ní òru, ninu ọ̀wọ̀n iná láti máa fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ kí wọ́n lè máa rìn ní ọ̀sán ati ní òru. +Ọ̀wọ̀n ìkùukùu kò fi ìgbà kan kúrò níwájú àwọn eniyan náà ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀wọ̀n iná ní òru. +Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ranti ọjọ́ òní tíí ṣe ọjọ́ tí ẹ jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti inú ìgbèkùn, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mu yín jáde kúrò níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí wọ́n fi ìwúkàrà sí. +Òní ni ọjọ́ pé tí ẹ óo jáde kúrò ní Ijipti, ninu oṣù Abibu. +Nígbà tí Ọlọrun bá mu yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí ó ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fi fún yín, tí ó kún fún wàrà ati oyin, ẹ óo máa ṣe ìsìn yìí ninu oṣù yìí lọdọọdun. +Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, ní ọjọ́ keje ẹ óo pe àpèjọ kan fún OLUWA láti ṣe àjọ̀dún. +Láàrin ọjọ́ meje tí ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, a kò gbọdọ̀ rí burẹdi tí ó ní ìwúkàrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni ninu yín, kò sì gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ní gbogbo agbègbè yín. +Kí olukuluku wí fún ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ náà pé, ‘Nítorí ohun tí OLUWA ṣe fún mi, nígbà tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá, ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe yìí.’ +Kí ó jẹ́ àmì ní ọwọ́ rẹ, ati ohun ìrántí láàrin ojú rẹ, kí òfin OLUWA lè wà ní ẹnu rẹ, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá. +Yíya Àwọn Àkọ́bí sí Mímọ́. +OLUWA bá rán Mose, ó ní, +Nígbà tí Farao súnmọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú sókè tí wọ́n rí àwọn ará Ijipti tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wọn; ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Wọ́n kígbe sí OLUWA; +wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Mose pé, “Ṣé kò sí ibojì ní Ijipti ni o fi kó wa kúrò láti wá kú sí ààrin aṣálẹ̀? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí, tí o kó wa kúrò ní Ijipti? +Ṣebí a sọ fún ọ ní Ijipti pé kí o fi wá sílẹ̀ kí á máa sin àwọn ará Ijipti tí à ń sìn, nítorí pé kì bá sàn kí á máa sin àwọn ará Ijipti ju kí á wá kú sinu aṣálẹ̀ lọ.” +Mose bá dá àwọn eniyan náà lóhùn, ó ní, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró gbọningbọnin, kí ẹ wá máa wo ohun tí OLUWA yóo ṣe. Ẹ óo rí i bí yóo ṣe gbà yín là lónìí; nítorí pé àwọn ará Ijipti tí ẹ̀ ń wò yìí, ẹ kò tún ní rí wọn mọ́ laelae. +OLUWA yóo jà fún yín, ẹ̀yin ẹ ṣá dúró jẹ́.” +OLUWA wí fún Mose pé, “Kí ló dé tí o fi ń ké pè mí, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n tẹ̀síwájú. +Gbé ọ̀pá rẹ sókè kí o na ọwọ́ sórí Òkun Pupa, kí ó sì pín in sí meji, kí àwọn eniyan Israẹli lè kọjá láàrin rẹ̀ lórí ìyàngbẹ ilẹ̀. +N óo mú kí ọkàn àwọn ará Ijipti le, kí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn ọmọ Israẹli wọ inú Òkun Pupa, n óo sì gba ògo lórí Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. +Àwọn ará Ijipti yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá gba ògo lórí Farao ati kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.” +Angẹli Ọlọrun tí ó ti wà níwájú àwọn eniyan Israẹli bá bọ́ sẹ́yìn wọn, ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó wà níwájú wọn náà bá pada sí ẹ̀yìn wọn. +“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n yipada, kí wọ́n sì pàgọ́ siwaju Pi Hahirotu, láàrin Migidoli ati Òkun Pupa, níwájú Baali Sefoni; ẹ pàgọ́ yín siwaju rẹ̀ lẹ́bàá òkun. +Ọ̀wọ̀n ìkùukùu náà sì wà láàrin àwọn ọmọ ogun Ijipti ati àwọn ọmọ ogun Israẹli, ìkùukùu náà ṣókùnkùn dudu títí tí gbogbo òru ọjọ́ náà fi kọjá, wọn kò sì súnmọ́ ara wọn. +Mose na ọwọ́ rẹ̀ sórí Òkun Pupa; OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ líle kan fẹ́ wá láti ìhà ìlà oòrùn ní gbogbo òru náà, afẹ́fẹ́ náà bi omi òkun sẹ́yìn, ó sì mú kí ààrin òkun náà di ìyàngbẹ ilẹ̀, omi rẹ̀ sì pín sí ọ̀nà meji. +Àwọn ọmọ Israẹli bọ́ sí ààrin òkun náà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi òkun wá dàbí ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ní ẹ̀gbẹ́ òsì wọn. +Àwọn ará Ijipti lé wọn wọ inú òkun, tàwọn ti gbogbo ẹṣin Farao ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati gbogbo ẹlẹ́ṣin rẹ̀. +Nígbà tí ó di òwúrọ̀ kutukutu, OLUWA bojú wo ogun Ijipti láti òkè wá, ninu ọ̀wọ̀n iná, ati ọ̀wọ̀n ìkùukùu, ó sì dẹ́rùbà wọ́n. +Ó mú kí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọ́n há, tí ó fi jẹ́ pé àwọn kẹ̀kẹ́ náà wúwo rinrin. Àwọn ọmọ ogun Ijipti bá wí láàrin ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun ń bá wa jà nítorí wọn.” +Ọlọrun bá sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun pupa kí omi lè bo àwọn ará Ijipti ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn, ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn mọ́lẹ̀.” +Mose bá na ọwọ́ sórí òkun, òkun bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣàn tẹ́lẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji yóo fi mọ́; àwọn ará Ijipti gbìyànjú láti jáde, ṣugbọn OLUWA pa wọ́n run sinu òkun náà. +Omi òkun pada sí ipò rẹ̀, ó sì bo gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin, ati àwọn ọmọ ogun Farao tí wọ́n lépa àwọn ọmọ Israẹli wọ inú Òkun Pupa, ẹyọ kan kò sì yè ninu wọn. +Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli rìn kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ ninu Òkun Pupa, omi rẹ̀ sì dàbí ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ní ẹ̀gbẹ́ òsì wọn. +Nítorí Farao yóo wí pé, ‘Ilẹ̀ ti ká àwọn eniyan Israẹli mọ́, aṣálẹ̀ sì ti sé wọn mọ́.’ +Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe gba Israẹli lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ní ọjọ́ náà, àwọn ọmọ Israẹli sì rí i bí àwọn ará Ijipti ti kú sí etí bèbè òkun. +Àwọn ọmọ Israẹli rí ohun ńlá tí OLUWA ṣe sí àwọn ará Ijipti, wọ́n bẹ̀rù OLUWA, wọ́n sì gba OLUWA gbọ́, ati Mose, iranṣẹ rẹ̀. +N óo tún mú kí ọkàn Farao le, yóo lépa yín, n óo sì gba ògo lórí Farao ati ogun rẹ̀, àwọn ará Ijipti yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bí OLUWA ti wí. +Nígbà tí wọ́n sọ fún Farao, ọba Ijipti, pé àwọn ọmọ Israẹli ti sálọ, èrò òun ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ nípa àwọn eniyan náà yipada. Wọ́n wí láàrin ara wọn pé, “Irú kí ni a ṣe yìí, tí a jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi lọ mọ́ wa lọ́wọ́, tí a kò jẹ́ kí wọ́n ṣì máa sìn wá?” +Nítorí náà Farao ní kí wọ́n tọ́jú kẹ̀kẹ́ ogun òun, ó sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ. +Ó ṣa ẹgbẹta (600) kẹ̀kẹ́ ogun tí ó dára, ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ilẹ̀ Ijipti yòókù, ó sì yan àwọn olórí ogun tí yóo máa ṣe àkóso wọn. +OLUWA mú ọkàn Farao, ọba Ijipti le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń lọ tìgboyà-tìgboyà. +Àwọn ará Ijipti ń lé wọn lọ, pẹlu gbogbo ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun Farao, ati gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ati gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀, wọ́n bá wọn níbi tí wọ́n pàgọ́ sí lẹ́bàá òkun, lẹ́bàá Pi Hahirotu ni òdìkejì Baali Sefoni. +Líla Òkun Pupa Kọjá. +Lẹ́yìn náà, Mose ati àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLUWA, wọ́n ní: “N óo kọrin sí OLUWA,nítorí pé, ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo.Àtẹṣin, àtẹni tí ń gùn ún ni ó dà sinu Òkun Pupa. +Ṣugbọn o fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n,òkun sì bò wọ́n mọ́lẹ̀,wọ́n rì bí òjé ninu ibú ńlá. +“Ta ló dàbí rẹ OLUWA ninu àwọn oriṣa?Ta ló dàbí rẹ, ológo mímọ̀ jùlọ?Ẹlẹ́rù níyìn tíí ṣe ohun ìyanu. +O na ọwọ́ ọ̀tún rẹ,ilẹ̀ sì yanu, ó gbé wọn mì. +O ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ṣe amọ̀nà àwọn eniyan rẹ tí o rà pada,o ti fi agbára rẹ tọ́ wọn lọ sí ibùgbé mímọ́ rẹ. +Àwọn eniyan ti gbọ́, wọ́n wárìrì,jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ Filistini. +Ẹnu ya àwọn ìjòyè Edomu,ojora sì mú gbogbo àwọn olórí ní ilẹ̀ Moabu,gbogbo àwọn tí ń gbé Kenaani sì ti kú sára. +Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati jìnnìjìnnì ti dà bò wọ́n,nítorí títóbi agbára rẹ, OLUWA,wọ́n dúró bí òkúta,títí tí àwọn eniyan rẹ fi kọjá lọ,àní àwọn tí o ti rà pada. +O óo kó àwọn eniyan rẹ wọlé,o óo sì fi ìdí wọn múlẹ̀ lórí òkè mímọ́ rẹ,níbi tí ìwọ OLUWA ti pèsè fún ibùgbé rẹ,ibi mímọ́ rẹ tí ìwọ OLUWA ti fi ọwọ́ ara rẹ pèsè sílẹ̀. +OLUWA yóo jọba títí lae ati laelae.” +Nígbà tí àwọn ẹṣin Farao, ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọ inú òkun, OLUWA mú kí omi òkun pada bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣugbọn àwọn eniyan Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ láàrin òkun. +OLUWA ni agbára ati orin mi, ó ti gbà mí là, òun ni Ọlọrun mi,n óo máa yìn ín.Òun ni Ọlọrun àwọn baba ńlá mi;n óo máa gbé e ga. +Nígbà náà ni Miriamu, wolii obinrin, tíí ṣe arabinrin Aaroni, gbé ìlù timbireli lọ́wọ́, gbogbo àwọn obinrin sì tẹ̀lé e, wọ́n ń lu timbireli, wọ́n sì ń jó. +Miriamu bá dá orin fún wọn pé,“Ẹ kọrin sí OLUWA,nítorí tí ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo,ó ti da ati ẹṣin ati àwọn ẹlẹ́ṣin sinu Òkun Pupa.” +Mose bá bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú láti ibi Òkun Pupa, wọ́n ń lọ sí aṣálẹ̀ Ṣuri, ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi rìn ninu aṣálẹ̀ láìrí omi. +Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi tí wọ́n rí níbẹ̀, nítorí pé ó korò. Nítorí náà, wọ́n sọ orúkọ ibẹ̀ ní Mara, ìtumọ̀ èyí tíí ṣe ìkorò. +Ni àwọn eniyan náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose, wọ́n ní, “Kí ni a óo mu?” +Mose bá kígbe sí OLUWA, OLUWA fi igi kan hàn án. Mose ju igi náà sinu omi, omi náà sì di dídùn. Ibẹ̀ ni OLUWA ti fún wọn ní ìlànà ati òfin, ó sì dán wọn wò, +ó ní, “Bí ẹ bá farabalẹ̀ gbọ́ ohùn èmi OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, tí ẹ pa gbogbo òfin mi mọ́, tí ẹ sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà mi, èmi OLUWA kò ní fi èyíkéyìí ninu àwọn àrùn tí mo fi ṣe àwọn ará Ijipti ṣe yín, nítorí pé, èmi ni OLUWA, olùwòsàn yín.” +Lẹ́yìn náà ni wọ́n dé Elimu, níbi tí orísun omi mejila ati aadọrin igi ọ̀pẹ wà, wọ́n sì pàgọ́ sẹ́bàá àwọn orísun omi náà. +Jagunjagun ni OLUWA, OLUWA sì ni orúkọ rẹ̀. +Ó da kẹ̀kẹ́ ogun Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sinu òkun,ó sì ri àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀ sinu Òkun Pupa. +Ìkún omi bò wọ́n mọ́lẹ̀,wọ́n rilẹ̀ sinu ibú omi bí òkúta. +Agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ pọ̀ jọjọ, OLUWA;OLUWA, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú. +Ninu títóbi ọláńlá rẹ, o dojú àwọn ọ̀tá rẹ bolẹ̀,o fa ibinu yọ, ó sì jó wọn bí àgékù koríko. +Èémí ihò imú rẹ mú kí omi gbájọ,ìkún omi dúró lóòró bí òkítì,ibú omi sì dì ní ìsàlẹ̀ òkun. +Ọ̀tá wí pé,‘N óo lé wọn, ọwọ́ mi yóo sì tẹ̀ wọ́n;n óo pín ìkógun,n óo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi lọ́rùn lára wọn.N óo fa idà mi yọ,ọwọ́ mi ni n óo sì fi pa wọ́n run.’ +Orin Mose. +Nígbà tí ó yá, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli jáde kúrò ní Elimu, wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini tí ó wà ní ààrin Elimu ati Sinai, ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keji tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti ni wọ́n dé aṣálẹ̀ náà. +Bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ eniyan Israẹli sọ̀rọ̀, wọ́n wo apá aṣálẹ̀, wọ́n sì rí i pé ògo OLUWA hàn ninu ìkùukùu. +OLUWA bá wí fún Mose pé, +“Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn, wí fún wọn pé, ‘Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ óo máa jẹ ẹran, ní òwúrọ̀, ẹ óo máa jẹ burẹdi ní àjẹyó. Nígbà náà ni ẹ óo tó mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.’ ” +Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ẹyẹ àparò fò dé, wọ́n sì bo gbogbo àgọ́ náà; nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, ìrì sẹ̀ bo gbogbo àgọ́ náà. +Nígbà tí ìrì náà kásẹ̀ nílẹ̀, wọ́n rí i tí kinní funfun kan tí ó dàbí ìrì dídì bo ilẹ̀ ní gbogbo aṣálẹ̀ náà. +Nígbà tí àwọn eniyan Israẹli rí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn léèrè pé, “Kí nìyí?” Nítorí pé, wọn kò mọ ohun tíí ṣe. Mose bá dá wọn lóhùn pé, “Oúnjẹ tí OLUWA fún yín láti jẹ ni. +Àṣẹ tí OLUWA pa ni pé, ‘Kí olukuluku yín kó ìwọ̀nba tí ó lè jẹ tán, kí ẹ kó ìwọ̀n Omeri kan fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu àgọ́ yín.’ ” +Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn mìíràn kó ju ohun tí ó yẹ kí wọ́n kó, àwọn mìíràn kò sì kó tó. +Ṣugbọn nígbà tí wọn fi ìwọ̀n Omeri wọ̀n ọ́n, àwọn tí wọ́n kó pupọ jù rí i pé, ohun tí wọ́n kó, kò lé nǹkankan; àwọn tí wọn kò sì kó pupọ rí i pé ohun tí wọ́n kó tó wọn; olukuluku kó ìwọ̀n tí ó lè jẹ. +Mose wí fún wọn pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣẹ́ ohunkohun kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.” +Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni ninu aṣálẹ̀, +Ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí Mose lẹ́nu; àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, ohun tí wọ́n ṣẹ́kù ti bẹ̀rẹ̀ sí yọ ìdin, ó sì ń rùn, Mose bá bínú sí wọn. +Ní àràárọ̀ ni olukuluku máa ń kó ohun tí ó bá lè jẹ tán, nígbà tí oòrùn bá gòkè, gbogbo èyí tí ó bá wà nílẹ̀ yóo sì yọ́ dànù. +Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹfa, wọ́n kó ìlọ́po meji, olukuluku kó ìwọ̀n Omeri meji meji. Nígbà tí àwọn àgbààgbà Israẹli lọ sọ fún Mose, +ó wí fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘Ọ̀la ni ọjọ́ ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀, ọjọ́ ìsinmi mímọ́ fún OLUWA. Ẹ dín ohun tí ẹ bá fẹ́ dín, kí ẹ sì se ohun tí ẹ bá fẹ́ sè, ohun tí ó bá ṣẹ́kù, ẹ fi pamọ́ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.’ ” +Wọ́n bá fi ìyókù pamọ́ títí di òwúrọ̀ gẹ́gẹ́ bí Mose ti sọ fún wọn; kò sì rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò yọ ìdin. +Mose wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ èyí lónìí, nítorí pé òní ni ọjọ́ ìsinmi OLUWA, ẹ kò ní rí kó rárá ní òní. +Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi máa rí oúnjẹ kó, ṣugbọn ní ọjọ́ keje tíí ṣe ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí níbẹ̀ rárá.” +Ní ọjọ́ keje, àwọn mìíràn ninu àwọn eniyan náà jáde láti lọ kó oúnjẹ, ṣugbọn wọn kò rí ohunkohun. +OLUWA bá wí fún Mose pé, “Yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo fi kọ̀ láti pa àṣẹ ati òfin mi mọ́. +Ẹ wò ó! OLUWA ti fún yín ní ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà ni ó fi jẹ́ pé, ní ọjọ́ kẹfa ó fún yín ní oúnjẹ fún ọjọ́ meji, kí olukuluku lè dúró sí ààyè rẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe jáde ní ilé rẹ̀ ní ọjọ́ keje.” +wọ́n ń wí pé, “Ìbá sàn kí OLUWA pa wá sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí olukuluku wa ti jókòó ti ìsaasùn ọbẹ̀ ��ran, tí a sì ń jẹ oúnjẹ àjẹyó, ju bí ẹ ti kó wa wá sí ààrin aṣálẹ̀ yìí lọ, láti fi ebi pa gbogbo wa kú.” +Àwọn eniyan náà bá sinmi ní ọjọ́ keje. +Àwọn eniyan Israẹli pe orúkọ oúnjẹ náà ní mana, ó rí rínbíntín-rínbíntín, ó dàbí èso igi korianda, ó funfun, ó sì dùn lẹ́nu bíi burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n fi oyin ṣe. +Mose wí fún wọn pé, “Àṣẹ tí OLUWA pa nìyí: ‘Ẹ fi ìwọ̀n omeri kan pamọ́ láti ìrandíran yín, kí àwọn ọmọ yín lè rí irú oúnjẹ tí mo fi bọ́ yín ninu aṣálẹ̀ nígbà tí mo ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá.’ ” +Mose bá sọ fún Aaroni pé, “Mú ìkòkò kan kí o fi ìwọ̀n omeri mana kan sinu rẹ̀, kí o gbé e kalẹ̀ níwájú OLUWA, kí ẹ pa á mọ́ láti ìrandíran yín.” +Aaroni bá gbé e kalẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA ti pa fún Mose. +Àwọn eniyan Israẹli jẹ mana náà fún ogoji ọdún, títí wọ́n fi dé ilẹ̀ tí wọ́n lè máa gbé, òun ni wọ́n jẹ títí tí wọ́n fi dé etí ilẹ̀ Kenaani. +Ìwọ̀n omeri kan jẹ́ ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa kan. +OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Wò ó, n óo rọ̀jò oúnjẹ fún yín láti ọ̀run. Kí àwọn eniyan máa jáde lọ ní ojoojumọ, kí wọ́n sì máa kó ìwọ̀nba ohun tí wọn yóo jẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. N óo fi èyí dán wọn wò, kí n fi mọ̀ bóyá wọn yóo máa tẹ̀lé òfin mi tabi wọn kò ní tẹ̀lé e. +Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹfa, kí wọ́n kó oúnjẹ wálé kí ó tó ìlọ́po meji èyí tí wọn ń kó ní ojoojumọ.” +Mose ati Aaroni bá sọ fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé, “Ní ìrọ̀lẹ́ òní ni ẹ óo mọ̀ pé OLUWA ló mú yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti. +Nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, ẹ óo rí ògo OLUWA, nítorí ó ti gbọ́ kíkùn tí ẹ̀ ń kùn sí i. Kí ni àwa yìí jẹ́, tí ẹ óo fi máa kùn sí wa?” +Mose ní, “OLUWA tìkararẹ̀ ni yóo fún yín ní ẹran ní ìrọ̀lẹ́, ati burẹdi ní òwúrọ̀. Ẹ óo jẹ àjẹyó, nítorí pé ó ti gbọ́ gbogbo kíkùn tí ẹ̀ ń kùn sí i; nítorí pé kí ni àwa yìí jẹ́? Gbogbo kíkùn tí ẹ̀ ń kùn, àwa kọ́ ni ẹ̀ ń kùn sí, OLUWA gan-an ni ẹ̀ ń kùn sí.” +Mose sọ fún Aaroni pé, “Sọ fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli pé, kí wọ́n súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ OLUWA, nítorí pé ó ti gbọ́ gbogbo kíkùn wọn.” +Mana ati Àparò. +Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli gbéra láti aṣálẹ̀ Sini, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti ibùsọ̀ kan dé ekeji, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn. Wọ́n pàgọ́ sí Refidimu, ṣugbọn kò sí omi fún wọn láti mu. +Joṣua ṣe bí Mose ti pàṣẹ fún un, ó bá àwọn ará Amaleki jagun. Mose ati Aaroni ati Huri bá gun orí òkè lọ. +Nígbà tí Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, àwọn ọmọ Israẹli a máa borí àwọn ará Amaleki, nígbà tí ó bá sì rẹ ọwọ́ sílẹ̀, àwọn ará Amaleki a máa borí àwọn ọmọ Israẹli. +Nígbà tí ó yá, apá bẹ̀rẹ̀ sí ro Mose, wọ́n gbé òkúta kan fún un láti fi jókòó, ó sì jókòó lórí rẹ̀. Aaroni ati Huri bá a gbé apá rẹ̀ sókè, ẹnìkan gbé apá ọ̀tún, ẹnìkejì sì gbé apá òsì. Apá rẹ̀ wà lókè títí tí oòrùn fi ń lọ wọ̀. +Joṣua bá fi idà pa Amaleki ati àwọn eniyan rẹ̀ ní ìpakúpa. +OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Kọ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sinu ìwé kan fún ìrántí, sì kà á sí etígbọ̀ọ́ Joṣua, pé n óo pa Amaleki rẹ́ patapata, a kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́ láyé.” +Mose bá tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni àsíá mi.” +Ó ní, “Gbé àsíá OLUWA sókè! OLUWA yóo máa bá ìrandíran àwọn ará Amaleki jà títí lae.” +Wọ́n bá ka ẹ̀sùn sí Mose lẹ́sẹ̀, wọ́n ní, “Fún wa ní omi tí a óo mu.”Mose dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ka ẹ̀sùn sí mi lẹ́sẹ̀? Kí ló dé tí ẹ sì fi ń dán OLUWA wò?” +Ṣugbọn òùngbẹ ń gbẹ àwọn eniyan náà, wọ́n fẹ́ mu omi, wọ́n bá ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi òùngbẹ pa àwa ati àwọn ọmọ wa, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa?” +Mose bá tún kígbe pe OLUWA, ó ní, “Kí ni n óo ṣe sí àwọn eniyan wọnyi, wọ́n ti múra láti sọ mí lókùúta.” +OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú ninu àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Israẹli lọ́wọ́, kí ẹ jọ la ààrin àwọn eniyan náà kọjá, kí o sì mú ọ̀pá tí o fi lu odò Naili lọ́wọ́, bí o bá ti ń lọ. +N óo dúró níwájú rẹ lórí àpáta ní òkè Horebu. Nígbà tí o bá fi ọ̀pá lu àpáta náà, omi yóo ti inú rẹ̀ jáde, àwọn eniyan náà yóo sì mu ún.” Mose bá ṣe bẹ́ẹ̀ níwájú gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli. +Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Masa ati Meriba, nítorí ìwà ìka-ẹ̀sùn-síni-lẹ́sẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli hù, ati nítorí dídán tí wọn dán OLUWA wò, wọ́n ní, “Ṣé OLUWA tún wà láàrin wa ni tabi kò sí mọ́?” +Lẹ́yìn èyí ni àwọn ará Amaleki wá, wọ́n sì bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní Refidimu. +Mose bá wí fún Joṣua pé, “Yan àwọn akọni ọkunrin láàrin yín kí o sì jáde lọ láti bá àwọn ará Amaleki jagun lọ́la, n óo dúró ní orí òkè pẹlu ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ mi.” +Omi Jáde láti Inú Àpáta. +Jẹtiro, alufaa àwọn ará Midiani, baba iyawo Mose, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọrun ti ṣe fún Mose ati fún Israẹli, àwọn eniyan rẹ̀, ati bí ó ti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. +Jẹtiro dáhùn, ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA, tí ó gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ati lọ́wọ́ Farao. +Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ó ti gba àwọn eniyan náà lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, nígbà tí àwọn ará Ijipti ń lò wọ́n ní ìlò àbùkù ati ẹ̀gàn.” +Jẹtiro bá rú ẹbọ sísun sí Ọlọrun. Aaroni ati àwọn àgbààgbà Israẹli sì wá sọ́dọ̀ Jẹtiro, láti bá a jẹun níwájú Ọlọrun. +Ní ọjọ́ keji, Mose jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan wà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti òwúrọ̀ títí di àṣáálẹ́. +Nígbà tí baba iyawo Mose rí gbogbo ohun tí Mose ń ṣe fún àwọn eniyan, ó pè é, ó ní, “Kí ni gbogbo ohun tí ò ń ṣe fún àwọn eniyan wọnyi? Kí ló dé tí o fi wà lórí àga ìdájọ́ láti òwúrọ̀ títí di àṣáálẹ́, tí àwọn eniyan ń kó ẹjọ́ wá bá ìwọ nìkan?” +Mose dáhùn pé, “Ọ̀dọ̀ mi ni àwọn eniyan náà ti máa ń bèèrè ohun tí Ọlọrun fẹ́ kí wọ́n ṣe. +Nígbà tí èdè-àìyedè bá wà láàrin àwọn aládùúgbò meji, èmi ni mo máa ń parí rẹ̀ fún wọn. Èmi náà ni mo sì máa ń sọ òfin Ọlọrun, ati àwọn ìpinnu rẹ̀ fún wọn.” +Baba iyawo rẹ̀ bá bá a wí pé, “Ohun tí ò ń ṣe yìí kò dára. +Àtìwọ àtàwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ, ẹ óo pa ara yín; ohun tí ò ń ṣe yìí ti pọ̀ jù fún ọ, o kò lè dá a ṣe. +Gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí, ìmọ̀ràn ni mo fẹ́ gbà ọ́, Ọlọrun yóo sì wà pẹlu rẹ. Ó dára kí o máa ṣe aṣojú àwọn eniyan náà níwájú Ọlọrun, kí o sì máa bá wọn kó ẹ̀dùn ọkàn wọn tọ Ọlọrun lọ; +Jẹtiro, baba iyawo Mose mú Sipora aya Mose, lẹ́yìn tí Mose ti dá a pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀ tẹ́lẹ̀, +ó sì dára bákan náà pẹlu kí o máa kọ́ wọn ní òfin ati ìlànà, kí o sì máa fi ọ̀nà tí wọn yóo tọ̀ hàn wọ́n, ati ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe. +Ohun tí ó yẹ kí o ṣe nìyí, yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jẹ́ alákòóso, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun, tí wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, tí wọ́n sì kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀; fi wọ́n ṣe alákòóso àwọn eniyan wọnyi, fi àwọn kan ṣe alákòóso lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn kan lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn kan lórí araadọta, ati àwọn mìíràn lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá. +Jẹ́ kí wọn máa ṣe onídàájọ́ fún àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá jẹ́ pataki pataki nìkan ni wọn yóo máa kó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, kí wọ́n máa parí àwọn ẹjọ́ kéékèèké láàrin ara wọn. Èyí yóo mú kí ó rọ̀ ọ́ lọ́rùn, wọn yóo sì máa bá ọ gbé ninu ẹrù náà. +Bí Ọlọrun bá gbà fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí o sì ṣe é, ẹ̀mí rẹ yóo gùn, gbogbo àwọn eniyan wọnyi náà yóo sì pada sí ilé wọn ní alaafia.” +Mose gba ọ̀rọ̀ tí baba iyawo rẹ̀ sọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí ó fún un. +Mose yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè ṣe alákòóso ninu àwọn eniyan Israẹli, ó fi wọ́n ṣe olórí àwọn eniyan náà, àwọn kan jẹ́ alákòóso fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn, fún ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn, fún araadọta, àwọn mìíràn fún eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá. +Wọ́n ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá fẹ́ díjú nìkan ni wọ́n ń kó tọ Mose lọ, wọ́n ń yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké láàrin ara wọn. +Mose gbà fún baba iyawo rẹ̀ pé kí ó máa pada lọ sí ìlú rẹ̀, baba iyawo rẹ̀ gbéra, ó sì pada sí orílẹ̀-èdè rẹ̀. +ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeeji. Orúkọ ọmọ rẹ̀ kinni ni Geriṣomu, (ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Mo ti jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”) +Orúkọ ọmọ keji ni Elieseri, (ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ọlọrun baba mi ni olùrànlọ́wọ́ mi, òun ni ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ idà Farao.”) +Jẹtiro, baba iyawo Mose, mú iyawo Mose, ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji tọ̀ ọ́ wá ní aṣálẹ̀, níbi tí wọ́n pàgọ́ sí níbi òkè Ọlọrun. +Nígbà tí wọ́n sọ fún Mose pé Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu iyawo rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, +Mose lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀ níwájú Jẹtiro, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, wọ́n bèèrè alaafia ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ. +Gbogbo ohun tí Ọlọrun ṣe sí Farao ati sí àwọn ará Ijipti nítorí àwọn ọmọ Israẹli ni Mose ròyìn fún baba iyawo rẹ̀. Ó sọ gbogbo ìṣòro tí wọ́n rí lójú ọ̀nà, ati bí OLUWA ti kó wọn yọ. +Jẹtiro sì bá wọn yọ̀ nítorí gbogbo oore tí OLUWA ti ṣe fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí gbígbà tí ó gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti. +Jẹtiro Lọ Bẹ Mose Wò. +Ní oṣù kẹta tí àwọn eniyan Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n dé aṣálẹ̀ Sinai. +OLUWA bá dá Mose lóhùn, ó ní, “Tọ àwọn eniyan náà lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ lónìí ati lọ́la. Sọ fún wọn pé kí wọ́n fọ aṣọ wọn, kí wọ́n wà ní ìmúrasílẹ̀ ní ọjọ́ kẹta, +nítorí pé ní ọjọ́ kẹta yìí ni èmi OLUWA óo sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, lójú gbogbo wọn. +Pààlà yípo òkè náà fún wọn, kí o sì kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọ́n ṣọ́ra, kí wọ́n má ṣe gun òkè yìí, tabi fi ọwọ́ kan ẹsẹ̀ òkè náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè yìí, pípa ni n óo pa á. +Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kàn án, òkúta ni kí wọ́n sọ pa á tabi kí wọ́n ta á ní ọfà; kì báà ṣe ẹranko tabi eniyan, dandan ni kí ó kú. Nígbà tí fèrè bá dún, tí dídún rẹ̀ pẹ́, kí wọn wá sí ẹ̀bá òkè náà.” +Mose bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ó tọ àwọn eniyan náà lọ, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. +Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ múrasílẹ̀ di ọ̀tunla, ẹ má ṣe súnmọ́ obinrin láti bá a lòpọ̀.” +Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, ààrá bẹ̀rẹ̀ sí sán, bẹ́ẹ̀ ni mànàmáná ń kọ, ìkùukùu sì bo òkè náà mọ́lẹ̀, fèrè kan dún tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo eniyan tí wọ́n wà ninu àgọ́ wárìrì. +Mose bá kó àwọn eniyan náà jáde láti pàdé Ọlọrun, wọ́n sì dúró ní ẹsẹ̀ òkè. +Èéfín bo gbogbo òkè Sinai mọ́lẹ̀, nítorí pé ninu iná ni OLUWA ti sọ̀kalẹ̀ sórí rẹ̀, ọ̀wọ̀n èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ bí ọ̀wọ̀n èéfín iná ìléru ńlá, gbogbo òkè náà sì mì tìtì. +Bí fèrè ti ń dún kíkankíkan tí dídún rẹ̀ sì ń gòkè sí i, bẹ́ẹ̀ ni Mose ń sọ̀rọ̀, Ọlọrun sì ń fi ààrá dá a lóhùn. +Refidimu ni wọ́n ti gbéra wá sí aṣálẹ̀ Sinai. Nígbà tí wọ́n dé aṣálẹ̀ yìí, wọ́n pàgọ́ wọn siwaju òkè Sinai. +OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, ó dúró ní ṣóńṣó òkè náà, ó pe Mose sọ́dọ̀, Mose sì gòkè tọ̀ ọ́ lọ. +OLUWA sọ fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o sì kìlọ̀ fún àwọn eniyan náà, kí wọ́n má baà rọ́ wọ ibi tí OLUWA wà láti wò ó, kí ọpọlọpọ wọn má baà parun. +Ati pé, kí àwọn alufaa tí yóo súnmọ́ ibi tí OLUWA wà, ya ara wọn sí mímọ́, kí n má baà jẹ wọ́n níyà.” +Mose bá dá OLUWA lóhùn pé, “OLUWA, àwọn eniyan wọnyi kò lè gun òkè Sinai wá, nítorí pé ìwọ náà ni o pàṣẹ pé kí á pààlà yí òkè náà po, kí á sì yà á sí mímọ́.” +OLUWA sì wí fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o mú Aaroni gòkè wá, ṣugbọn má ṣe jẹ́ kí àwọn alufaa ati àwọn eniyan náà rọ́ wá sórí òkè níbi tí mo wà, kí n má baà jẹ wọ́n níyà.” +Mose bá sọ̀kalẹ̀ lọ bá àwọn eniyan náà, ó sì jíṣẹ́ fún wọn. +Mose bá gòkè tọ Ọlọrun lọ.OLUWA pè é láti orí òkè náà, ó ní, “Ohun tí mo fẹ́ kí o sọ fún àwọn ọmọ Israẹli nìyí, +‘Ṣé ẹ rí ohun tí èmi OLUWA fi ojú àwọn ará Ijipti rí, ati bí mo ti fi ẹ̀yìn pọ̀n yín títí tí mo fi kó yín wá sí ọ̀dọ̀ mi níhìn-ín? +Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì pa majẹmu mi mọ́ ẹ óo jẹ́ tèmi láàrin gbogbo eniyan, nítorí pé tèmi ni gbogbo ayé yìí patapata; +ẹ óo di ìran alufaa ati orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.’ Bẹ́ẹ̀ ni kí o sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.” +Mose bá pada wá, ó pe àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, ó sì sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un fún wọn. +Gbogbo àwọn eniyan náà bá pa ohùn pọ̀, wọ́n ní, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe.” Mose bá lọ sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA. +OLUWA sọ fún Mose pé, “Mò ń tọ̀ ọ́ bọ̀ ninu ìkùukùu tí yóo bo gbogbo ilẹ̀, kí àwọn eniyan náà lè gbọ́ nígbà tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì lè gbà ọ́ gbọ́ títí lae.”Mose sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA. +Àwọn Ọmọ Israẹli ní Òkè Sinai. +Ní àkókò náà, ọkunrin kan láti inú ẹ̀yà Lefi fẹ́ obinrin kan tí òun náà jẹ́ ẹ̀yà Lefi. +Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó gbé e pada fún ọmọbinrin Farao, ó sì fi ṣe ọmọ, ó sọ ọ́ ní Mose, ó wí pé, “Nítorí pé láti inú omi ni mo ti fà á jáde.” +Nígbà tí Mose dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ó sì rí i bí ìyà tí ń jẹ wọ́n. Ó rí i tí ará Ijipti kan ń lu ọ̀kan ninu àwọn Heberu, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. +Nígbà tí ó wo ọ̀tún, tí ó wo òsì, tí kò rí ẹnìkankan, ó lu ará Ijipti náà pa, ó sì bò ó mọ́ inú yanrìn. +Nígbà tí ó tún jáde lọ ní ọjọ́ keji, ó rí i tí àwọn Heberu meji ń jà; ó bá bi ẹni tí ó jẹ̀bi pé, “Kí ló dé tí o fi ń lu ẹnìkejì rẹ?” +Ọkunrin náà dáhùn pé, “Ta ló fi ọ́ jẹ olórí ati onídàájọ́ wa? Ṣé o fẹ́ pa èmi náà bí o ti pa ará Ijipti níjelòó ni?” Ẹ̀rù ba Mose, ó sì rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Láìsí àní àní, ọ̀rọ̀ yìí ti di mímọ̀.” +Nígbà tí Farao gbọ́, ó ń wá ọ̀nà àtipa Mose. Ṣugbọn Mose sálọ mọ́ ọn lọ́wọ́, ó lọ sí ilẹ̀ Midiani, ó sì jókòó lẹ́bàá kànga kan. +Àwọn ọmọbinrin meje kan wá pọn omi, wọ́n jẹ́ ọmọ Jẹtiro, alufaa ìlú Midiani. Wọ́n pọn omi kún ọpọ́n ìmumi àwọn ẹran, láti fún àwọn agbo ẹran baba wọn ní omi mu. +Nígbà tí àwọn olùṣọ́-aguntan dé, wọ́n lé àwọn ọmọbinrin meje náà sẹ́yìn; ṣugbọn Mose dìde, ó ran àwọn ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ó sì fún àwọn ẹran wọn ní omi mu. +Nígbà tí wọ́n pada dé ọ̀dọ̀ Reueli, baba wọn, ó bi wọ́n pé, “Ó ṣe ya yín tó báyìí lónìí?” +Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Ijipti kan ni ó gbà wá kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan náà, ó tilẹ̀ tún bá wa pọn omi fún agbo ẹran wa.” +Obinrin náà lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Nígbà tí ó rí i pé ọmọ náà jẹ́ arẹwà, ó gbé e pamọ́ fún oṣù mẹta. +Reueli bá bi àwọn ọmọ rẹ̀ léèrè pé, “Níbo ni ará Ijipti ọ̀hún wà? Kí ló dé tí ẹ fi sílẹ̀? Ẹ lọ pè é wọlé, kí ó wá jẹun.” +Mose gbà láti máa gbé ọ̀dọ̀ ọkunrin náà, ó bá fún un ní Sipora, ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin rẹ̀ láti fi ṣe aya. +Ó bí ọmọkunrin kan, ó sì sọ ọmọ náà ní Geriṣomu, ó wí pé, “Mo jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.” +Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún, ọba Ijipti kú, àwọn ọmọ Israẹli sì ń kérora ní oko ẹrú tí wọ́n wà, wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́. Igbe tí wọn ń ké ní oko ẹrú sì gòkè tọ OLUWA lọ. +Ọlọrun gbọ́ ìkérora wọn, ó sì ranti majẹmu tí ó bá Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu dá. +Ọlọrun bojú wo àwọn eniyan Israẹli, ó sì rí irú ipò tí wọ́n wà. +Nígbà tí kò lè gbé e pamọ́ mọ́, ó fi koríko kan tí ó dàbí èèsún ṣe apẹ̀rẹ̀ kan, ó fi oje igi ati ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ, ó gbé ọmọ náà sinu rẹ̀, ó sì gbé apẹ̀rẹ̀ náà sí ààrin koríko lẹ́bàá odò. +Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obinrin dúró ní òkèèrè, ó ń wo ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i. +Láìpẹ́, ọmọbinrin Farao lọ wẹ̀ ní odò náà, àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ sì ń rìn káàkiri etídò. Ó rí apẹ̀rẹ̀ náà láàrin koríko, ó bá rán iranṣẹbinrin rẹ̀ lọ gbé apẹ̀rẹ̀ náà. +Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ọmọ kan ninu rẹ̀, ọmọ náà ń sọkún. Àánú ṣe é, ó wí pé, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Heberu nìyí.” +Ẹ̀gbọ́n ọmọ náà bá bi ọmọbinrin Farao pé, “Ṣé kí n lọ pe olùtọ́jú kan wá lára àwọn obinrin Heberu, kí ó máa bá ọ tọ́jú ọmọ yìí?” +Ọmọbinrin Farao dá a lóhùn pé, “Lọ pè é wá.” Ọmọbinrin náà bá yára lọ pe ìyá ọmọ náà. +Ọmọbinrin Farao sọ fún ìyá ọmọ náà pé, “Gbé ọmọ yìí lọ, kí o máa bá mi tọ́jú rẹ̀, n óo sì san owó àgbàtọ́ rẹ̀ fún ọ.” Bẹ́ẹ̀ ni obinrin náà ṣe gba ọmọ, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. +Ìbí Mose. +Ọlọrun sì sọ ọ̀rọ̀ wọnyii, ó ní, +Ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí olukuluku níláti yà sọ́tọ̀ fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà; olukuluku yín ati ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, ati ẹrú rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, ati ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati àlejò tí ó wà ninu ilé rẹ̀. +Nítorí pé, ọjọ́ mẹfa ni èmi OLUWA fi dá ọ̀run ati ayé, ati òkun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn; mo sì sinmi ní ọjọ́ keje. Nítorí náà ni mo ṣe bukun ọjọ́ ìsinmi náà, tí mo sì yà á sí mímọ́. +“Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn lórí ilẹ̀ tí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ fi fún ọ. +“O kò gbọdọ̀ paniyan. +“O kò gbọdọ̀ ṣe panṣaga. +“O kò gbọdọ̀ jalè. +“O kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnikeji rẹ. +“O kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ọmọnikeji rẹ, tabi sí aya rẹ̀ tabi sí iranṣẹ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, tabi sí akọ mààlúù rẹ̀, tabi sí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tabi sí ohunkohun tí ó jẹ́ ti ọmọnikeji rẹ.” +Nígbà tí àwọn eniyan náà gbọ́ bí ààrá ti ń sán, tí wọ́n rí i bí mànàmáná ti ń kọ, tí wọ́n gbọ́ dídún ìró fèrè, tí wọ́n rí i tí òkè ń rú èéfín, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì wárìrì. Wọ́n dúró lókèèrè, +wọ́n sì wí fún Mose pé, “Ìwọ ni kí o máa bá wa sọ̀rọ̀, a óo máa gbọ́; má jẹ́ kí Ọlọrun bá wa sọ̀rọ̀ mọ́, kí a má baà kú.” +“Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ní oko ẹrú tí ẹ wà: +Mose bá dá àwọn eniyan náà lóhùn pé, “Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín, Ọlọrun wá dán yín wò ni, kí ẹ lè máa bẹ̀rù rẹ̀, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀.” +Àwọn eniyan náà dúró lókèèrè, bí Mose tí ń súnmọ́ òkùnkùn biribiri tí ó ṣú bo ibi tí Ọlọrun wà. +OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Ẹ ti rí i fúnra yín pé mo ba yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá. +Ẹ kò gbọdọ̀ fi wúrà tabi fadaka yá ère láti máa bọ, àfi èmi nìkan ni kí ẹ máa sìn. +Yẹ̀ẹ̀pẹ̀ ni kí ẹ fi tẹ́ pẹpẹ fún mi, kí ẹ sì máa rú ẹbọ sísun yín ati ẹbọ alaafia yín lórí rẹ̀, kì báà ṣe aguntan tabi mààlúù. Níbikíbi tí mo bá pa láṣẹ pé kí ẹ ti sìn mí, n óo tọ̀ yín wá, n óo sì súre fún yín níbẹ̀. +Bí ẹ bá fi òkúta tẹ́ pẹpẹ fún mi, ẹ má lo òkúta tí wọ́n bá gbẹ́, nítorí pé bí ẹ bá fi ohun èlò yín ṣiṣẹ́ lára òkúta náà, ẹ ti sọ ọ́ di aláìmọ́. +Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ́ pẹpẹ tí ẹ óo máa fi àtẹ̀gùn gùn, kí wọ́n má baà máa rí ìhòòhò yín lórí rẹ̀. +“O kò gbọdọ̀ ní ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. +“O kò gbọdọ̀ yá èrekére fún ara rẹ, kì báà ṣe àwòrán ohun tí ó wà ní òkè ọ̀run, tabi ti ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀, tabi ti ohun tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀. +O kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bọ wọ́n; nítorí Ọlọrun tí í máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ẹ̀ṣẹ̀ baba bi ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ẹkẹrin lára àwọn tí wọ́n kórìíra mi. +Ṣugbọn èmi a máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn tí wọ́n fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́. +“O kò gbọdọ̀ pe orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ lásán, nítorí pé, èmi OLUWA yóo dá ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ mi lásán lẹ́bi. +“Ranti ọjọ́ ìsinmi kí o sì yà á sí mímọ́. +Ọjọ́ mẹfa ni kí olukuluku máa fi ṣiṣẹ́, kí ó sì máa fi parí ohun tí ó bá níláti ṣe. +Òfin Mẹ́wàá. +“Àwọn òfin tí o gbọdọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: +Bí ó bá fẹ́ aya mìíràn fún ara rẹ̀, kò gbọdọ̀ dín oúnjẹ ẹrubinrin yìí kù, tabi aṣọ rẹ̀ tabi àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aya. +Bí olówó ẹrubinrin yìí bá kọ̀, tí kò ṣe àwọn nǹkan mẹtẹẹta náà fún ẹrubinrin rẹ̀, ẹrubinrin náà lẹ́tọ̀ọ́ láti jáde ní ilé rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìsan ohunkohun. +“Bí ẹnikẹ́ni bá lu eniyan pa, pípa ni a óo pa òun náà. +Ṣugbọn bí olúwarẹ̀ kò bá mọ̀ọ́nmọ̀ pa á, tí ó jẹ́ pé ó ṣèèṣì ni, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ibìkan tí n óo yàn fún yín. +Ṣugbọn bí ẹnìkan bá mọ̀ọ́nmọ̀ bá ẹlòmíràn jà, tí ó sì fi ọgbọ́n àrékérekè pa á, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sálọ sí ibi pẹpẹ mi, fífà ni kí ẹ fà á kúrò níbi pẹpẹ náà kí ẹ sì pa á. +“Ẹnikẹ́ni tí ó bá lu baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa òun náà. +“Ẹnikẹ́ni tí ó bá jí eniyan gbé, kì báà jẹ́ pé ó ti tà á, tabi kí wọ́n ká a mọ́ ọn lọ́wọ́, pípa ni kí wọ́n pa á. +“Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé baba tabi ìyá rẹ̀ ṣépè, pípa ni kí wọ́n pa á. +“Bí eniyan meji bá ń jà, tí ọ̀kan bá fi òkúta tabi ẹ̀ṣẹ́ lu ekeji, tí ẹni tí wọ́n lù náà kò bá kú, ṣugbọn tí ó farapa, +bí ẹni tí wọ́n lù tí ó farapa náà bá dìde, tí ó sì ń fi ọ̀pá rìn kiri, ẹni tí ó lù ú bọ́ lọ́wọ́ ikú, ṣugbọn dandan ni kí ó san owó fún àkókò tí ẹni tí ó lù náà lò ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, kí ó sì ṣe ètò ìtọ́jú rẹ̀ títí yóo fi sàn. +Bí ẹnikẹ́ni bá ra Heberu kan lẹ́rú, ọdún mẹfa ni ẹrú náà óo fi sìn ín, ní ọdún keje, ó níláti dá a sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìgba ohunkohun lọ́wó�� rẹ̀. +“Bí ẹnìkan bá lu ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀ ní kùmọ̀, tí ẹrú náà bá kú mọ́ ọn lọ́wọ́, olúwarẹ̀ yóo jìyà. +Ṣugbọn bí ẹrú náà bá gbé odidi ọjọ́ kan tabi meji kí ó tó kú, kí ẹnikẹ́ni má jẹ olówó ẹrú náà níyà, nítorí òun ni ó ni owó tí ó fi rà á. +“Bí àwọn eniyan bá ń jà, tí wọ́n sì ṣe aboyún léṣe, tóbẹ́ẹ̀ tí oyún rẹ̀ bàjẹ́ mọ́ ọn lára, ṣugbọn tí òun gan-an kò kú, ẹni tí ó ṣe aboyún náà léṣe níláti san iyekíye tí ọkọ rẹ̀ bá sọ pé òun yóo gbà bí owó ìtanràn, tí onídàájọ́ bá ti fi ọwọ́ sí i. +Ṣugbọn bí aboyún náà bá kú tabi bí ó bá farapa, kí wọ́n pa ẹni tí ó ṣe é léṣe náà. +Bí ẹnìkan bá fọ́ eniyan lójú, kí wọ́n fọ́ ojú tirẹ̀ náà; bí ẹnìkan bá ká eniyan léyín, kí wọ́n ká eyín tirẹ̀ náà, bí ẹnìkan bá gé eniyan lọ́wọ́, kí wọ́n gé ọwọ́ tirẹ̀ náà, bí ẹnìkan bá gé eniyan lẹ́sẹ̀, kí wọ́n gé ẹsẹ̀ tirẹ̀ náà. +Bí ẹnìkan bá fi iná jó eniyan, kí wọ́n fi iná jó òun náà, bí ẹnìkan bá ṣá eniyan lọ́gbẹ́, kí wọ́n ṣá òun náà lọ́gbẹ́, bí ẹnìkan bá na eniyan lẹ́gba, kí wọ́n na òun náà lẹ́gba. +“Bí ẹnìkan bá gbá ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀ lójú, tí ojú náà sì fọ́, olúwarẹ̀ yóo dá ẹrú náà sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìgba ohunkohun lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí pé ó ti fọ́ ọ lójú. +Bí ó bá yọ eyín ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀, yóo dá ẹrú náà sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí pé ó ti yọ ọ́ léyín. +“Bí mààlúù bá kan eniyan pa, kí wọ́n sọ mààlúù náà ní òkúta pa. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀; ṣugbọn kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ ẹni tí ó ni mààlúù náà níyà. +Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ mààlúù náà ti kan eniyan tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti kìlọ̀ fún ẹni tí ó ni ín, tí kò sì so ó mọ́lẹ̀, bí ó bá pa eniyan, kí wọn sọ mààlúù náà ní òkúta pa, kí wọn sì pa ẹni tí ó ni ín pẹlu. +Bí ó bá jẹ́ pé òun nìkan ni ó rà, òun nìkan ni òfin dá sílẹ̀, ṣugbọn bí ẹrú náà bá mú aya rẹ̀ lọ́wọ́ wá, bí ó bá ti ń dá a sílẹ̀, ó gbọdọ̀ dá aya rẹ̀ sílẹ̀ pẹlu. +Ṣugbọn bí wọ́n bá gbà pé kí ẹni tí ó ni ín san owó ìtanràn, ó níláti san iyekíye tí wọ́n bá sọ pé kí ó san, kí ó baà lè ra ẹ̀mí ara rẹ̀ pada. +Bí irú mààlúù tí ó ti kan eniyan pa tẹ́lẹ̀ rí yìí bá tún kan ọmọ ẹnìkan pa, kì báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, irú ẹ̀tọ́ kan náà tí a sọ yìí ni wọ́n gbọdọ̀ ṣe fún ẹni tí ó ni mààlúù náà. +Bí mààlúù náà bá kan ẹrú ẹnìkan pa, kì báà ṣe ẹrukunrin tabi ẹrubinrin, ẹni tí ó ni mààlúù náà níláti san ọgbọ̀n ṣekeli fadaka fún ẹni tí ó ni ẹrú tí mààlúù pa, kí wọ́n sì sọ mààlúù náà ní òkúta pa. +“Bí ẹnìkan bá gbẹ́ kòtò sílẹ̀, tí kò bá bò ó, tabi tí ó gbẹ́ kòtò tí kò sì dí i, bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi mààlúù bá já sinu kòtò yìí, tí ó sì kú, +ẹni tí ó gbẹ́ kòtò yìí gbọdọ̀ san owó mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún ẹni tí ó ni ín, òkú ẹran yìí yóo sì di ti ẹni tí ó gbẹ́ kòtò. +Bí mààlúù ẹnìkan bá pa ti ẹlòmíràn, àwọn mejeeji yóo ta mààlúù tí ó jẹ́ ààyè, wọn yóo pín owó rẹ̀, wọn yóo sì pín òkú mààlúù náà pẹlu. +Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé mààlúù yìí ti máa ń kàn tẹ́lẹ̀, tí ẹni tí ó ni ín kò sì mú un so, yóo fi mààlúù mìíràn rọ́pò èyí tí mààlúù rẹ̀ pa, òkú mààlúù yóo sì di tirẹ̀. +Bí olówó rẹ̀ bá fẹ́ aya fún un, tí aya náà sì bímọ fún un, lọkunrin ati lobinrin, olówó rẹ̀ ni ó ni aya ati àwọn ọmọ patapata, òun nìkan ni òfin dá sílẹ̀. +Ṣugbọn bí ẹrú náà bá fúnra rẹ̀ wí ní gbangba pé òun fẹ́ràn olówó òun, ati aya òun, ati àwọn ọmọ òun, nítorí náà òun kò ní gba ìdásílẹ̀, kí òun má baà fi wọ́n sílẹ̀, +olówó rẹ̀ yóo mú un wá siwaju Ọlọrun, ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ tabi òpó ìlẹ̀kùn, olówó rẹ̀ yóo fi òòlù lu ihò sí etí rẹ̀, ẹrú náà yóo sì di tirẹ̀ títí ayé. +“Bí ẹnìkan bá ta ọmọ rẹ̀ obinrin lẹ́rú, ẹrubinrin yìí kò ní jáde bí ẹrukunrin. +Bí ẹrubinrin yìí kò bá wù olówó rẹ̀ láti fi ṣe aya, ó níláti dá a pada fún baba rẹ̀, baba rẹ̀ yóo sì rà á pada. Olówó rẹ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á fún àjèjì nítorí pé òun ló kọ̀ tí kò ṣe ẹ̀tọ́ fún un. +Bí ó bá fẹ́ ẹ sọ́nà fún ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ó gbọdọ̀ ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ gan-an. +Ojúṣe Olówó Ẹrú sí Ẹrú. +“Bí ẹnìkan bá jí akọ mààlúù kan tabi aguntan kan gbé, tí ó bá pa á, tabi tí ó tà á, yóo san akọ mààlúù marun-un dípò ẹyọ kan ati aguntan mẹrin dípò aguntan kan. Tí kò bá ní ohun tí yóo fi tán ọ̀ràn náà, wọn yóo ta òun fúnra rẹ̀ láti san ohun tí ó jí. +“Bí ẹnìkan bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní ẹran sìn, kì báà ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi mààlúù, tabi aguntan, bí ẹran náà bá kú tabi kí ó farapa, tabi tí ó bá rìn lọ tí kò sì sí ẹni tí ó rí i, +aládùúgbò náà yóo lọ sí ilé Ọlọrun, yóo sì fi OLUWA ṣẹ̀rí pé òun kọ́ ni òun jí ẹran tí wọn fún òun sìn. Ẹni tí ó fún un ní ẹran sìn yóo faramọ́ ìbúra yìí, kò sì ní gbẹ̀san mọ́. +Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé wọ́n jí i gbé mọ́ ọn lọ́wọ́ ni, yóo san ẹ̀san fún ẹni tí ó ni ín. +Bí ó bá jẹ́ pé ẹranko burúkú ni ó pa á, bí ó bá ní ohun tí ó lè fi ṣe ẹ̀rí, tí ó sì fi ohun náà han ẹni tí ó ni ẹran náà, kò ní san ẹ̀san ẹran náà pada. +“Bí ẹnìkan bá yá ẹran ọ̀sìn kẹ́ran ọ̀sìn lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹran náà bá farapa tabi tí ó kú, tí kò sì sí olówó ẹran náà níbẹ̀, ẹni tí ó yá ẹran náà níláti san án pada. +Ṣugbọn bí ẹni tí ó ni ẹran náà bá wà níbẹ̀ nígbà tí ó kú, ẹni tí ó yá a kò ní san ẹ̀san pada. Bí ó bá jẹ́ pé owó ni wọ́n fi yá ẹran náà lọ tí ó fi kú, a jẹ́ pé orí iṣẹ́ owó rẹ̀ ni ó kú sí. +“Bí ẹnìkan bá tan wundia tí kì í ṣe àfẹ́sọ́nà ẹnikẹ́ni, tí ó sì bá wundia náà lòpọ̀, ó gbọdọ̀ san owó orí rẹ̀ kí ó sì gbé e níyàwó. +Bí baba wundia náà bá kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò ní fi ọmọ òun fún un, yóo san iye owó tí wọ́n bá ń san ní owó orí wundia tí kò mọ ọkunrin. +“Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àjẹ́ wà láàyè. +“Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹranko lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa á. +Bí a bá ká olè mọ́ ibi tí ó ti ń fọ́lé lóru, tí a sì lù ú pa, ẹni tí ó lù ú pa kò jẹ̀bi. +“Ẹnikẹ́ni tí ó bá rúbọ sí oriṣa-koriṣa kan lẹ́yìn OLUWA, píparun ni kí wọ́n pa á run. +“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú tabi kí ó ni ín lára, nítorí pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. +Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fìyà jẹ opó tabi aláìníbaba. +Bí ẹnikẹ́ni bá fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n bá ké pè mí, dájúdájú n óo gbọ́ igbe wọn; +ibinu mi yóo sì ru sí yín, n óo fi idà pa yín, àwọn aya yín yóo di opó, àwọn ọmọ yín yóo sì di aláìníbaba. +“Bí o bá yá ẹnikẹ́ni lówó ninu àwọn eniyan mi, tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, tí ó ṣe aláìní, má ṣe bí àwọn tí wọn ń fi owó wọn gba èlé, má gba èlé lórí owó tí o yá a. +Bí aládùúgbò rẹ bá fi ẹ̀wù rẹ̀ dógò lọ́dọ̀ rẹ, tí o sì gbà á, dá a pada fún un kí oòrùn tó wọ̀; +nítorí pé ẹ̀wù yìí ni àwọ̀lékè kan ṣoṣo tí ó ní, òun kan náà sì ni aṣọ ìbora rẹ̀. Àbí aṣọ wo ni ó tún ní tí yóo fi bora sùn? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ké pè mí, n óo dá a lóhùn, nítorí pé aláàánú ni mí. +“O kò gbọdọ̀ kẹ́gàn Ọlọrun, o kò sì gbọdọ̀ gbé ìjòyè àwọn eniyan rẹ ṣépè. +“O kò gbọdọ̀ jáfara láti mú ninu ọpọlọpọ ọkà rẹ ati ọpọlọpọ ọtí waini rẹ láti fi rúbọ sí mi.“O níláti fún mi ní àkọ́bí rẹ ọkunrin pẹlu. +Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ pé lojumọmọ ni, ẹ̀bi wà fún ẹni tí ó lù ú pa. Ṣugbọn tí ọwọ́ bá tẹ olè lojumọmọ, ó níláti san ohun tí ó jí pada. +Bákan náà ni àkọ́bí mààlúù rẹ ati ti aguntan rẹ, tí wọ́n bá jẹ́ akọ. Fi wọ́n sílẹ̀ pẹlu ìyá wọn fún ọjọ́ meje, ní ọjọ́ kẹjọ o níláti fi wọ́n rúbọ sí mi. +“Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí a yà sọ́tọ̀ fún mi, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ òkú ẹran tí ẹranko bá pa ninu ìgbẹ́, ajá ni kí ẹ gbé irú ẹran bẹ́ẹ̀ fún. +Bí wọ́n bá ká ẹran ọ̀sìn tí olè jí gbé mọ́ ọn lọ́wọ́ láàyè, kì báà ṣe akọ mààlúù, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tabi aguntan; ìlọ́po meji ni yóo fi san pada. +“Bí ẹnìkan bá jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ jẹ oko olóko, tabi ọgbà àjàrà ẹlòmíràn, tabi tí ó bá da ẹran wọ inú oko olóko tí wọ́n sì jẹ nǹkan ọ̀gbìn inú rẹ̀, ibi tí ó dára jùlọ ninu oko tabi ọgbà àjàrà tirẹ̀ ni yóo fi dí i fún ẹni tí ó ni oko tabi ọgbà àjàrà tí ẹran rẹ̀ jẹ. +“Bí ẹnìkan bá dáná, tí iná náà bá ràn mọ́ koríko, tí ó bá jó oko olóko, tí ó sì jó ọkà tí wọ́n ti kórè jọ tabi tí ó wà lóòró, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ san òmíràn pada fún olóko. +“Bí ẹnìkan bá fi owó tabi ìṣúra kan pamọ́ sí ọwọ́ aládùúgbò rẹ̀, tí olè bá gbé e lọ mọ́ aládùúgbò rẹ̀ yìí lọ́wọ́, bí ọwọ́ bá tẹ olè yìí, ìlọ́po meji ohun tí ó gbé ni yóo fi san. +Bí ọwọ́ kò bá wá tẹ olè, ẹni tí ó gba ìṣúra pamọ́ yìí gbọdọ̀ wá sí ilé Ọlọrun kí ó fi Ọlọrun ṣẹ̀rí pé òun kò fi ọwọ́ kan ìṣúra tí aládùúgbò òun fi pamọ́ sí òun lọ́wọ́. +“Nígbàkúùgbà tí ohun ìní bá di àríyànjiyàn láàrin eniyan meji, kì báà jẹ́ mààlúù, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tabi aguntan, tabi aṣọ, tabi ohunkohun tí ó bá ti sọnù, tí ó sì di àríyànjiyàn, àwọn mejeeji tí wọn ń lọ́ nǹkan mọ́ ara wọn lọ́wọ́ gbọdọ̀ wá sí ilé Ọlọrun, kí wọ́n sì fi Ọlọrun ṣẹ̀rí, ẹni tí Ọlọrun bá dá lẹ́bi yóo san ìlọ́po meji nǹkan náà fún ẹnìkejì rẹ̀. +Òfin nípa Sísan Ẹ̀san. +“O kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí àhesọ tí kò ní òtítọ́ ninu. O kò gbọdọ̀ bá eniyan burúkú pa ìmọ̀ pọ̀ láti jẹ́rìí èké. +“Ọdún mẹfa ni kí o fi máa fúnrúgbìn sórí ilẹ̀ rẹ kí o sì fi máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ̀. +Ṣugbọn ní ọdún keje, o gbọdọ̀ fi oko náà sílẹ̀ kí ó sinmi, kí àwọn talaka ninu yín náà lè rí oúnjẹ jẹ, kí àwọn ẹranko sì jẹ ninu èyí tí àwọn talaka bá jẹ kù. Bẹ́ẹ̀ ni o gbọdọ̀ ṣe ọgbà àjàrà rẹ, ati ọgbà olifi rẹ pẹlu. +“Ọjọ́ mẹfa ni kí o fi ṣe iṣẹ́, ṣugbọn ní ọjọ́ keje, kí o sinmi; àtìwọ ati akọ mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ; kí ara lè tu ọmọ iranṣẹbinrin rẹ ati àlejò rẹ. +“Máa ṣe akiyesi gbogbo ohun tí mo ti sọ fún ọ, má sì ṣe bọ oriṣa kankan, má tilẹ̀ jẹ́ kí n gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu rẹ. +“Ìgbà mẹta ni o níláti máa ṣe àjọ̀dún fún mi ní ọdọọdún. +O níláti máa ṣe àjọ̀dún àìwúkàrà; gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni o gbọdọ̀ fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ ninu oṣù Abibu, nítorí pé ninu oṣù náà ni o jáde ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo. +“O gbọdọ̀ ṣe àjọ̀dún ìkórè nígbà tí o bá kórè àkọ́so àwọn ohun tí o gbìn sinu oko rẹ. “Ní òpin ọdún, nígbà tí o bá parí ìkórè gbogbo èso oko rẹ, o gbọdọ̀ ṣe àjọ̀dún ìkórè. +Ẹẹmẹta ní ọdọọdún ni gbogbo ọkunrin yín níláti wá siwaju èmi OLUWA Ọlọrun yín. +“Nígbà tí o bá fi ohun ẹlẹ́mìí rúbọ sí mi, burẹdi tí o bá fi rúbọ pẹlu rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí kò ní ìwúkàrà ninu, ọ̀rá ẹran tí o bá fi rúbọ sí mi kò sì gbọdọ̀ kù di ọjọ́ keji. +“Ohunkohun tí o bá kọ́ kórè ninu oko rẹ, ilé OLUWA Ọlọrun rẹ ni o gbọdọ̀ mú un wá.“O kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi wàrà ìyá rẹ̀. +O kò gbọdọ̀ bá ọ̀pọ̀ eniyan kẹ́gbẹ́ láti ṣe ibi, tabi kí o tẹ̀lé ọ̀pọ̀ eniyan láti jẹ́rìí èké tí ó lè yí ìdájọ́ po. +“Wò ó, mo rán angẹli kan ṣiwaju rẹ láti pa ọ́ mọ́ ní ọ̀nà rẹ, ati láti mú ọ wá sí ibi tí mo ti tọ́jú fún ọ. +Máa fetí sí ohun tí angẹli náà bá sọ fún ọ, kí o sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu, má ṣe fi agídí ṣe ìfẹ́ inú rẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé èmi ni mo rán an, kò sì ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. +Ṣugbọn bí o bá gbọ́ tirẹ̀, tí o sì ṣe bí mo ti wí, nígbà náà ni n óo gbógun ti àwọn tí ó bá gbógun tì ọ́, n óo sì dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá rẹ. +Nígbà tí angẹli mi bá ń lọ níwájú rẹ, tí ó bá mú ọ dé ilẹ̀ àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Perisi, ati ti àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí mo bá sì pa wọ́n run, +o kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún àwọn oriṣa wọn, o kò sì gbọdọ̀ bọ wọ́n, tabi kí o hu irú ìwà ìbọ̀rìṣà tí àwọn ará ibẹ̀ ń hù. Wíwó ni kí o wó àwọn ilé oriṣa wọn lulẹ̀, kí o sì fọ́ gbogbo àwọn òpó wọn túútúú. +Èmi OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ máa sìn. N óo pèsè ọpọlọpọ nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu fún yín, n óo sì mú àìsàn kúrò láàrin yín. +Ẹyọ oyún kan kò ní bàjẹ́ lára àwọn obinrin yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ obinrin kan kò ní yàgàn ninu gbogbo ilẹ̀ yín. N óo jẹ́ kí ẹ gbó, kí ẹ sì tọ́. +“N óo da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń lọ dojú ìjà kọ, rúdurùdu yóo sì bẹ́ sí ààrin wọn, gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa sálọ, nígbàkúùgbà tí wọ́n bá gbúròó yín. +N óo rán àwọn agbọ́n ńlá ṣáájú yín, tí yóo lé àwọn ará Hifi ati àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti jáde fún yín. +N kò ní tíì lé wọn jáde fún ọdún kan, kí ilẹ̀ náà m�� baà di aṣálẹ̀, kí àwọn ẹranko sì pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo gba gbogbo ilẹ̀ náà mọ́ yín lọ́wọ́. +O kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju sí talaka lórí ẹjọ́ rẹ̀. +Díẹ̀díẹ̀ ni n óo máa lé wọn jáde fún yín, títí tí ẹ óo fi di pupọ tí ẹ óo sì gba gbogbo ilẹ̀ náà. +Ilẹ̀ yín yóo lọ títí kan Òkun Pupa, ati títí lọ kan òkun àwọn ará Filistia, láti aṣálẹ̀ títí lọ kan odò Yufurate, nítorí pé n óo fi àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà le yín lọ́wọ́, ẹ óo sì lé wọn jáde. +Ẹ kò gbọdọ̀ bá àwọn tabi àwọn oriṣa wọn dá majẹmu. +Wọn kò gbọdọ̀ gbé orí ilẹ̀ yín, kí wọ́n má baà mú yín ṣẹ èmi OLUWA; nítorí pé bí ẹ bá bọ oriṣa wọn, ọrùn ara yín ni ẹ tì bọ tàkúté.” +“Bí o bá pàdé akọ mààlúù ọ̀tá rẹ tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ń ṣìnà lọ, o níláti fà á pada wá fún un. +Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹni tí ó kórìíra rẹ, tí ẹrù wó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà mọ́lẹ̀, tí kò lè lọ mọ́, o kò gbọdọ̀ gbójú kúrò kí o fi sílẹ̀ níbẹ̀, o níláti bá a sọ ẹrù náà kalẹ̀. +“O kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí talaka po nígbà tí ó bá ní ẹjọ́. +O kò gbọdọ̀ fi ẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni, o kò sì gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tabi olódodo nítorí pé, èmi, OLUWA kò ní dá eniyan burúkú láre. +O kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ àwọn aláṣẹ lójú, kì í jẹ́ kí wọn rí ẹ̀tọ́, a sì máa mú kí wọn sọ ẹjọ́ aláre di ẹ̀bi. +“O kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú, ẹ mọ̀ bí ọkàn àlejò ti rí, nítorí ẹ̀yin pàápàá jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. +Òdodo ati Ìṣòtítọ́. +OLUWA wí fún Mose pé, “Ẹ gòkè tọ èmi OLUWA wá, ìwọ ati Aaroni, ati Nadabu, ati Abihu, ati aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli, kí ẹ sì sin èmi OLUWA ní òkèèrè. +wọ́n sì rí Ọlọrun Israẹli. Wọ́n rí kinní kan ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó dàbí pèpéle tí a fi òkúta safire ṣe, ó mọ́lẹ̀ kedere bí ojú ọ̀run. +Ọlọrun kò sì pa àwọn àgbààgbà Israẹli náà lára rárá, wọ́n rí Ọlọrun, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu. +OLUWA wí fún Mose pé, “Gun orí òkè tọ̀ mí wá, kí o dúró sibẹ, n óo sì kó wàláà tí wọ́n fi òkúta ṣe fún ọ, tí mo kọ àwọn òfin ati ìlànà sí, fún ìtọ́ni àwọn eniyan yìí.” +Mose bá gbéra, òun ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ó gun orí òkè Ọlọrun lọ. +Ó sọ fún àwọn àgbààgbà pé, “Ẹ dúró níhìn-ín dè wá títí a óo fi pada wá bá yín. Aaroni ati Huri wà pẹlu yín, bí ẹnikẹ́ni bá ní àríyànjiyàn kan, kí ó kó o tọ̀ wọ́n lọ.” +Mose bá gun orí òkè náà lọ, ìkùukùu sì bo orí òkè náà. +Ògo OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, ìkùukùu sì bò ó fún ọjọ́ mẹfa, ní ọjọ́ keje, OLUWA pe Mose láti inú ìkùukùu náà. +Lójú àwọn eniyan Israẹli, ìrísí ògo OLUWA lórí òkè náà dàbí iná ńlá tí ń jóni ní àjórun. +Mose wọ inú ìkùukùu náà lọ, ó gun orí òkè náà, ó sì wà níbẹ̀ fún ogoji ọjọ́, tọ̀sán-tòru. +Ìwọ Mose nìkan ni kí o súnmọ́ mi, kí àwọn yòókù má ṣe súnmọ́ mi, má sì jẹ́ kí àwọn eniyan ba yín gòkè wá rárá.” +Mose bá tọ àwọn eniyan náà lọ, ó sọ gbogbo ohun tí OLUWA sọ fún un fún wọn, ati gbogbo ìlànà tí ó là sílẹ̀, gbogbo àwọn eniyan náà sì fi ẹnu kò, wọ́n dáhùn pé, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe.” +Mose bá kọ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ kutukutu, ó dìde, ó tẹ́ pẹpẹ kan sí ìsàlẹ̀ òkè náà, ó ri ọ̀wọ̀n mejila mọ́lẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan. +Ó sì rán àwọn kan ninu àwọn ọdọmọkunrin Israẹli, pé kí wọ́n lọ fi mààlúù rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. +Mose gba ìdajì ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran náà sinu àwo ńlá, ó sì da ìdajì yòókù sí ara pẹpẹ náà. +Ó mú ìwé majẹmu náà, ó kà á sí etígbọ̀ọ́ gbogbo àwọn eniyan, wọ́n sì dáhùn pé, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe, a óo sì gbọ́ràn.” +Ni Mose bá gba ẹ̀jẹ̀ ẹran yòókù tí ó wà ninu àwo, ó wọ́n ọn sí àwọn eniyan náà lára, ó ní, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí OLUWA bá yín dá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí mo sọ.” +Mose ati Aaroni, ati Nadabu, ati Abihu, ati aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli bá gòkè lọ, +Wọ́n fi Èdìdì Di Majẹmu Wọn Pẹlu Ọlọrun. +OLUWA rán Mose ó ní, +“Kí wọ́n fi igi akasia kan àpótí kan, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji ààbọ̀, kí ó fẹ̀ ní igbọnwọ kan ààbọ̀, kí ó sì ga ní igbọnwọ kan ààbọ̀. +Fi ojúlówó wúrà bò ó ninu ati l��de, kí o sì fi wúrà gbá a létí yípo. +Fi wúrà ṣe òrùka mẹrin, kí o jó wọn mọ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹrẹẹrin; meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji. +Fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì fi wúrà bò wọ́n. +Kí o ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji àpótí náà láti máa fi gbé e. +Kí àwọn ọ̀pá yìí máa wà ninu àwọn òrùka tí ó wá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí yìí nígbà gbogbo, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fà wọ́n yọ. +Kí o fi àkọsílẹ̀ majẹmu ẹ̀rí tí n óo gbé lé ọ lọ́wọ́ sinu àpótí náà. +“Lẹ́yìn náà, fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji ààbọ̀, kí ó sì fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ kan ààbọ̀. +Fi wúrà tí wọ́n fi ọmọ owú lù ṣe Kerubu meji, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìtẹ́ àánú náà. +Àṣepọ̀ mọ́ ìtẹ́ àánú ni kí o ṣe àwọn Kerubu náà, kí ọ̀kan wà ní ìsàlẹ̀, kí ekeji sì wà ní òkè rẹ̀. +“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n gba ọrẹ jọ fún mi, ọwọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ọkàn rẹ̀ wá láti ṣe ọrẹ àtinúwá ni kí wọ́n ti gba ọrẹ náà. +Kí àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú, kí wọ́n kọjú sí ara wọn, kí àwọn mejeeji sì máa wo ìtẹ́ àánú náà. +Gbé ìtẹ́ àánú náà ka orí àpótí náà, kí o sì fi ẹ̀rí majẹmu tí n óo fún ọ sinu rẹ̀. +Níbẹ̀ ni n óo ti máa pàdé rẹ; láti òkè ìtẹ́ àánú, ní ààrin àwọn Kerubu mejeeji tí wọ́n wà lórí àpótí ẹ̀rí ni n óo ti máa bá ọ sọ nípa gbogbo òfin tí mo bá fẹ́ fún àwọn eniyan Israẹli. +“Fi igi akasia kan tabili kan, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji, kí ó fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ kan, kí ó sì ga ní ìwọ̀n igbọnwọ kan ààbọ̀. +Yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, kí o sì yọ́ ojúlówó wúrà sí gbogbo etí rẹ̀ yípo. +Lẹ́yìn náà, ṣe ìgbátí kan yíká etí tabili náà, kí ó fẹ̀ ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan, kí o sì yọ́ wúrà bo ìgbátí náà yípo. +Lẹ́yìn náà, ṣe òrùka wúrà mẹrin, kí o sì jó òrùka kọ̀ọ̀kan mọ́ ibi ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan. +Kí òrùka kọ̀ọ̀kan súnmọ́ ìgbátí tabili náà, òrùka wọnyi ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé tabili náà. +Fi igi akasia ṣe ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n; àwọn ọ̀pá wọnyi ni wọn yóo máa fi gbé tabili náà. +Fi ojúlówó wúrà ṣe àwọn àwo ati àwo kòtò fún turari ati ìgò ati abọ́ tí wọn yóo fi máa ta ohun mímu sílẹ̀ fún ètùtù. +Àwọn nǹkan ọrẹ tí wọn yóo gbà lọ́wọ́ wọn ni: wúrà, fadaka, idẹ; +Gbé tabili náà kalẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, kí burẹdi ìfihàn sì máa wà ní orí rẹ̀ nígbà gbogbo. +“Fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà kan. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe é ní àṣepọ̀ mọ́ òkè ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà bí òdòdó tí wọn yóo fi dárà sí ìdí fìtílà kọ̀ọ̀kan. +Ṣe ẹ̀ka mẹfa sára ọ̀pá fìtílà náà, mẹta ní ẹ̀gbẹ́ kinni, ati mẹta ní ẹ̀gbẹ́ keji. +Kí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa yìí ní iṣẹ́ ọnà bí òdòdó aláràbarà mẹta mẹta tí ó dàbí òdòdó alimọndi. +Kí òdòdó aláràbarà mẹrin wà lórí ọ̀pá fìtílà náà gan-an, kí àwọn òdòdó náà dàbí alimọndi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ so, +kí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èso kéékèèké kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ẹ̀ka meji meji tí ó ya lára ọ̀pá fìtílà náà. +Àṣepọ̀ ni kí wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà, ati àwọn ẹ̀ka rẹ̀, ati àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èso kékeré abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀. Ojúlówó wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n sì fi ṣe gbogbo rẹ̀. +Ṣe fìtílà meje fún ọ̀pá fìtílà náà, kí o sì gbé wọn ka orí ọ̀pá náà ní ọ̀nà tí gbogbo wọn yóo fi kọjú siwaju. +Ojúlówó wúrà ni kí o fi ṣe ẹnu rẹ̀ ati àwo pẹrẹsẹ rẹ̀, +talẹnti wúrà kan ni kí o fi ṣe ọ̀pá fìtílà náà ati gbogbo ohun èlò rẹ̀. +aṣọ aláró, aṣọ elése àlùkò, aṣọ pupa, aṣọ funfun, ati irun ewúrẹ́; +Rí i dájú pé o ṣe gbogbo rẹ̀ pátá bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè. +awọ àgbò tí wọ́n ṣe, tí ó jẹ́ pupa, ati ti ewúrẹ́, igi akasia; +òróró fún àwọn fìtílà, ati àwọn èròjà olóòórùn dídùn fún òróró tí wọn ń ta sí eniyan lórí, ati turari, +òkúta onikisi ati àwọn òkúta tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ ọnà sára efodu tí àwọn alufaa ń wọ̀, ati ohun tí wọn ń dà bo àyà; +kí wọ́n sì ṣe ibùgbé fún mi, kí n lè máa gbé ààrin wọn. +Bí mo ti júwe fún ọ gan-an ni kí o ṣe àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èl�� inú rẹ̀. +Ọrẹ fún Àgọ́ Mímọ́. +“Aṣọ títa mẹ́wàá ni kí o fi ṣe inú àgọ́ mi, kí aṣọ náà jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, kí wọ́n dárà sí aṣọ náà pẹlu àwọ̀ aró, ati àwọ̀ elése àlùkò ati àwọ̀ pupa, kí àwọn tí wọ́n bá mọ iṣẹ́ ọnà ya àwòrán Kerubu sí ara gbogbo aṣọ títa náà. +Ṣe aadọta ojóbó sí awẹ́ tí ó parí àránpọ̀ aṣọ kinni, kí o sì ṣe aadọta ojóbó sí etí awẹ́ tí ó parí aṣọ àránpọ̀ keji. +Fi idẹ ṣe aadọta ìkọ́, kí o sì fi wọ́n kọ́ àwọn ojóbó náà, láti mú àwọn àránpọ̀ aṣọ mejeeji náà papọ̀ kí wọ́n lè jẹ́ ìbòrí kan. +Jẹ́ kí ìdajì awẹ́ tí ó kù ṣẹ́ bo ẹ̀yìn àgọ́ náà. +Jẹ́ kí igbọnwọ kọ̀ọ̀kan tí ó kù ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji àránpọ̀ aṣọ náà ṣẹ́ bo ẹ̀gbẹ́ kinni keji àgọ́ náà. +“Lẹ́yìn náà, fi awọ àgbò tí a ṣe ní pupa, ati awọ ewúrẹ́ tí a ṣe dáradára, ṣe ìbòrí keji fún àgọ́ náà. +“Igi akasia ni kí o fi ṣe àwọn òpó àgọ́ náà, +kí àwọn igi tí yóo dúró ní òòró gùn ní igbọnwọ mẹ́wàá, kí àwọn tí o óo fi dábùú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kọ̀ọ̀kan ààbọ̀. +Kí igi kọ̀ọ̀kan ní àtẹ̀bọ̀ meji, tí wọ́n tẹ̀ bọ inú ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe gbogbo àwọn igi tí wọ́n wà ninu àgọ́ náà. +Ogún àkànpọ̀ igi ni kí o ṣe sí ìhà gúsù àgọ́ náà. +Ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka ni kí o ṣe sí àwọn ogún àkànpọ̀ igi náà, ìtẹ́lẹ̀ meji meji sí àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan, kí ìtẹ́lẹ̀ meji wà fún àtẹ̀bọ̀ igi meji ninu olukuluku àkànpọ̀ igi náà. +Kí gígùn aṣọ títa kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlọgbọn, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, kí àwọn aṣọ títa náà gùn bákan náà, kí wọ́n sì fẹ̀ bákan náà. +Ṣe ogún àkànpọ̀ igi sí ẹ̀gbẹ́ àríwá àgọ́ náà, +ati ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka, meji meji sí àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan. +Àkànpọ̀ igi mẹfa ni kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn. +Kí o sì ṣe àkànpọ̀ igi meji meji fún igun mejeeji ẹ̀yìn àgọ́ náà. +Jẹ́ kí àwọn àkànpọ̀ igi mejeeji tí wọ́n wà ní igun àgọ́ wà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìsàlẹ̀, ṣugbọn kí o so wọ́n pọ̀ ní òkè ní ibi ìtẹ̀bọ̀ àkọ́kọ́. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe àwọn àkànpọ̀ igi mejeeji tí wọ́n wà ní igun mejeeji. +Gbogbo àkànpọ̀ igi yóo jẹ́ mẹjọ, ìtẹ́lẹ̀ fadaka wọn yóo sì jẹ́ mẹrindinlogun, meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan. +“Fi igi akasia ṣe igi ìdábùú mẹẹdogun; marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni àgọ́ náà, +marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ keji, marun-un yòókù fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀yìn ní apá ìwọ̀ oòrùn. +Kí igi ìdábùú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àkànpọ̀ igi náà gùn láti ẹ̀gbẹ́ kinni dé ẹ̀gbẹ́ keji àgọ́ náà. +Yọ́ wúrà bo àwọn àkànpọ̀ igi náà, kí wọ́n sì ní àwọn òrùka wúrà kí wọ́n lè máa ti àwọn igi ìdábùú náà bọ̀ ọ́, yọ́ wúrà bo àwọn igi ìdábùú náà pẹlu. +Rán marun-un ninu àwọn aṣọ títa náà pọ̀, lẹ́yìn náà, rán marun-un yòókù pọ̀. +Bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè, ni kí o ṣe kọ́ àgọ́ náà. +“Ṣe aṣọ títa kan, tí ó jẹ́ aláwọ̀ aró, ati elése àlùkò, ati pupa, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, kí wọ́n ya àwòrán Kerubu sí i lára. +Gbé e kọ́ sórí òpó igi akasia mẹrin, tí ó ní ìkọ́ wúrà. Wúrà ni kí o yọ́ bo gbogbo òpó náà, kí wọ́n sì wà lórí ìtẹ́lẹ̀ fadaka mẹrin. +Lára àwọn àtẹ̀bọ̀ ni kí o fi àwọn aṣọ títa náà kọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí náà wọ inú ibi tí aṣọ títa náà wà, aṣọ títa yìí ni yóo ya ibi mímọ́ sọ́tọ̀ kúrò lára ibi mímọ́ jùlọ. +Fi ìtẹ́ àánú sórí àpótí ẹ̀rí ninu ibi mímọ́ jùlọ. +Kí o gbé tabili kalẹ̀ ní ọwọ́ òde aṣọ títa náà, kí ọ̀pá fìtílà wà ní apá ìhà gúsù àgọ́ náà, ní òdìkejì tabili náà, kí o sì gbé tabili náà kalẹ̀ ní apá àríwá. +“Fi aṣọ aláwọ̀ aró ati elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí létí ṣe aṣọ títa kan fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà. +Ṣe òpó igi akasia marun-un fún aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà náà, kí o sì fi wúrà bo àwọn òpó náà; wúrà ni kí o fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn pẹlu, kí o sì ṣe ìtẹ́lẹ̀ idẹ marun-un fún wọn. +Fi aṣọ aláwọ̀ aró ṣe ojóbó sí etí ẹ̀gbẹ́ tí ó wà ní òde ninu aṣọ àránpọ̀ kọ̀ọ̀kan. +Aadọta ojóbó ni kí o ṣe sí àránpọ̀ aṣọ kinni, lẹ́yìn náà ṣe aadọta ojóbó sí àránpọ̀ aṣọ keji, kí àwọn ojóbó náà lè kọ ojú sí ara wọn. +Lẹ́yìn náà, ṣe aadọta ìkọ́ wúrà, kí o fi kọ́ àwọn ojóbó àránpọ̀ aṣọ mejeeji, kí àgọ́ náà lè dúró ní odidi kan ṣoṣo. +“Fi awẹ́ aṣọ mọkanla tí wọ́n fi irun ewúrẹ́ ṣe, ṣe ìbòrí kan fún àgọ́ náà. +Kí gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu aṣọ náà jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, kí àwọn aṣọ mọkọọkanla gùn bákan náà, kí wọ́n sì fẹ̀ bákan náà. +Rán marun-un ninu àwọn aṣọ náà pọ̀, lẹ́yìn náà, rán mẹfa yòókù pọ̀, kí o ṣẹ́ aṣọ kẹfa po bo iwájú àgọ́ náà. +Àgọ́ Wíwà OLUWA. +“Igi akasia ni kí o fi ṣe pẹpẹ, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un, kí ó sì fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un; kí òòró ati ìbú pẹpẹ náà rí bákan náà, kí ó sì ga ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹta. +àwọn òpó rẹ̀ yóo jẹ́ ogún, ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yóo sì jẹ́ ogún bákan náà, idẹ ni o óo fi ṣe wọ́n, ṣugbọn fadaka ni kí o fi ṣe àwọn ìkọ́ ati òpó rẹ̀. +Bákan náà, aṣọ tí o óo ta sí ẹ̀gbẹ́ àríwá àgbàlá náà yóo gùn ní ọgọrun-un igbọnwọ, àwọn òpó ti ẹ̀gbẹ́ náà yóo jẹ́ ogún bákan náà, pẹlu ogún ìtẹ́lẹ̀ tí a fi idẹ ṣe, ṣugbọn fadaka ni kí o fi ṣe ìkọ́ ati òpó wọn. +Aṣọ títa yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn àgbàlá náà, gígùn rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, yóo ní òpó mẹ́wàá, òpó kọ̀ọ̀kan yóo ní ìtẹ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan. +Fífẹ̀ àgbàlá náà, láti iwájú títí dé ẹ̀gbẹ́ ìlà oòrùn, yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ. +Aṣọ títa kan yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, yóo gùn ní igbọnwọ mẹẹdogun, yóo ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta. +Aṣọ títa kan yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ keji ẹnu ọ̀nà náà, òun náà yóo gùn ní igbọnwọ mẹẹdogun, yóo sì ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta bákan náà. +Ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà yóo ní aṣọ títa kan tí yóo gùn ní ogún igbọnwọ, aṣọ aláwọ̀ aró, èyí tí ó ní àwọ̀ elése àlùkò ati àwọ̀ pupa fòò ati aṣọ ọ̀gbọ̀ ni kí o fi ṣe aṣọ títa náà, kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí etí rẹ̀, kí ó ní òpó mẹrin ati ìtẹ́lẹ̀ mẹrin. +Fadaka ni kí o fi bo gbogbo òpó inú àgọ́ náà, fadaka náà ni kí o sì fi ṣe gbogbo ìkọ́ àwọn òpó náà, àfi àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ni kí o fi idẹ ṣe. +Gígùn àgbàlá náà yóo jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo sì jẹ́ igbọnwọ marun-un pẹlu aṣọ títa tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe ati ìtẹ́lẹ̀ idẹ. +Idẹ ni kí o fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò inú àgọ́ náà ati gbogbo èèkàn rẹ̀, ati gbogbo èèkàn àgbàlá náà. +Yọ ìwo kọ̀ọ̀kan sí igun rẹ̀ mẹrẹẹrin, àṣepọ̀ ni kí o ṣe àwọn ìwo náà mọ́ pẹpẹ, kí o sì yọ́ idẹ bo gbogbo rẹ̀. +“Pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli pé kí wọn mú ojúlówó òróró olifi wá fún títan iná, kí wọ́n lè gbé fìtílà kan kalẹ̀ tí yóo máa wà ní títàn nígbà gbogbo. +Yóo wà ninu àgọ́ àjọ, lọ́wọ́ ìta aṣọ títa tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ máa tọ́jú rẹ̀ níwájú OLUWA láti àṣáálẹ́ títí di òwúrọ̀. Kí àwọn eniyan Israẹli sì máa pa ìlànà náà mọ́ títí lae, láti ìrandíran. +Fi idẹ ṣe ìkòkò láti máa kó eérú orí pẹpẹ sí, fi idẹ ṣe ọkọ́, àwo kòtò, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń gún ẹran ẹbọ ati àwo ìfọnná, idẹ ni kí o fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò pẹpẹ náà. +Idẹ ni kí o fi ṣe asẹ́ ààrò rẹ̀, kí o sì ṣe òrùka idẹ mẹrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan sí igun mẹrẹẹrin asẹ́ náà. +Ti asẹ́ idẹ náà bọ abẹ́ etí pẹpẹ, tí yóo fi jẹ́ pé asẹ́ náà yóo dé agbede meji pẹpẹ náà sísàlẹ̀. +Fi igi akasia ṣe ọ̀pá pẹpẹ, kí o sì yọ́ idẹ bo ọ̀pá náà. +Kí o ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, tí ọ̀pá yóo fi wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé e. +Fi pákó ṣe pẹpẹ náà, kí o sì jẹ́ kí ó jin kòtò, bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe é. +“Ṣe àgbàlá kan sinu àgọ́ náà. Aṣọ ọ̀gbọ̀ ni kí o fi ṣe aṣọ títa apá gúsù àgbàlá náà, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ, +Pẹpẹ. +“Lẹ́yìn náà, pe Aaroni arakunrin rẹ sọ́dọ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ wọnyi: Nadabu, Abihu, Eleasari, ati Itamari. Yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n sì jẹ́ alufaa mi. +Orúkọ ẹ̀yà mẹfa sára òkúta ekinni ati orúkọ ẹ̀yà mẹfa yòókù sára ekeji, kí o to àwọn orúkọ ná�� bí wọ́n ṣe bí wọn tẹ̀lé ara wọn. +Bí oníṣẹ́ ọnà wúrà ti máa ń kọ orúkọ sí ara òrùka èdìdì, ni kí o kọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sí ara òkúta mejeeji, kí o sì fi wúrà ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn. +Lẹ́yìn náà, rán àwọn òkúta mejeeji mọ́ àwọn èjìká efodu náà, gẹ́gẹ́ bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli. Èyí yóo mú kí Aaroni máa mú orúkọ wọn wá siwaju OLUWA fún ìrántí. +O óo ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ wúrà, +ati ẹ̀wọ̀n wúrà meji tí a lọ́ pọ̀ bí okùn, kí o sì so àwọn ẹ̀wọ̀n wúrà náà mọ́ àwọn ìtẹ́lẹ̀ wúrà náà. +“Ṣe ìgbàyà ìdájọ́, èyí tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà dáradára sí lára, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọnà ara efodu náà: wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ni kí o fi ṣe é. +Bákan náà ni ìbú ati òòró rẹ̀ yóo rí, ìṣẹ́po meji ni yóo jẹ́, ìbú ati òòró rẹ̀ yóo sì jẹ́ ìká kọ̀ọ̀kan. +To òkúta olówó iyebíye sí ara rẹ̀ ní ẹsẹ̀ mẹrin, kí ẹsẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ òkúta sadiu, ati òkúta topasi, ati òkúta kabọnku. +Kí ẹsẹ̀ keji jẹ́ òkúta emeradi, ati òkúta safire, ati òkúta dayamọndi. +Kí ẹsẹ̀ kẹta jẹ́ òkúta jasiniti, ati òkúta agate, ati òkúta ametisti. +Sì dá ẹ̀wù mímọ́ kan fún Aaroni, arakunrin rẹ, kí ó lè fún un ní iyì ati ọlá. +Kí ẹsẹ̀ kẹrin jẹ́ òkúta bẹrili, ati òkúta onikisi, ati òkúta jasiperi, wúrà ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn òkúta wọnyi. +Oríṣìí òkúta mejila ni yóo wà, orúkọ wọn yóo dàbí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli; wọn yóo dàbí èdìdì, wọn yóo sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejila sí ara àwọn òkúta mejeejila, òkúta kan fún ẹ̀yà kan. +Fi ojúlówó wúrà ṣe ẹ̀wọ̀n tí a lọ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí okùn fún ìgbàyà náà. +Kí o da òrùka wúrà meji sí etí kinni keji ìgbàyà náà. +Fi ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji bọ inú òrùka mejeeji yìí. +So etí kinni keji àwọn ẹ̀wọ̀n mejeeji mọ́ ojú ìdè mejeeji, kí o so ó mọ́ èjìká efodu náà níwájú. +Da òrùka wúrà meji, sì dè wọ́n mọ́ etí kinni keji ìgbàyà náà lọ́wọ́ inú, ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kan ara efodu. +Lẹ́yìn náà, da òrùka wúrà meji mìíràn, kí o dè wọ́n mọ́ ìsàlẹ̀ àwọn èjìká efodu, níwájú ibi tí ó ti so pọ̀ mọ́ àmùrè rẹ̀. +Aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ aró ni wọn yóo máa fi bọ inú àwọn òrùka ara efodu ati àwọn òrùka ara ìgbàyà, láti dè wọ́n pọ̀ kí ó lè máa wà lórí àmùrè tí ó wà lára efodu náà, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu. +“Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli yóo máa wà lára Aaroni, lórí ìgbàyà ìdájọ́, ní oókan àyà rẹ̀, nígbà tí ó bá wọ ibi mímọ́ lọ, fún ìrántí nígbà gbogbo níwájú OLUWA. +Pe gbogbo àwọn tí wọ́n mọ iṣẹ́ ọnà jọ, àwọn tí mo fi ìmọ̀ ati òye iṣẹ́ ọnà dá lọ́lá, kí wọ́n rán aṣọ alufaa kan fún Aaroni láti yà á sọ́tọ̀ fún mi, gẹ́gẹ́ bí alufaa. +Fi òkúta Urimu ati òkúta Tumimu sí ara ìgbàyà ìdájọ́, kí wọn kí ó sì máa wà ní oókan àyà Aaroni, nígbà tí ó bá lọ siwaju OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni Aaroni yóo ṣe máa ru ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli sí oókan àyà rẹ̀, nígbà gbogbo níwájú OLUWA. +“O óo fi aṣọ aláwọ̀ aró rán ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ sí efodu náà. +Yọ ọrùn sí ẹ̀wù náà, kí o sì fi aṣọ bí ọ̀já tẹ́ẹ́rẹ́ gbá a lọ́rùn yípo, bí wọ́n ti máa ń fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ gbá ọrùn ẹ̀wù, kí ó má baà ya. +Fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ya àwòrán èso pomegiranate sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà nísàlẹ̀, sì fi agogo ojúlówó wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan la àwọn àwòrán èso pomegiranate náà láàrin, yípo etí àwọ̀kanlẹ̀ efodu náà, nísàlẹ̀. +Agogo wúrà kan, àwòrán èso pomegiranate kan, bẹ́ẹ̀ ni kí o tò wọ́n sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ efodu náà. +Èyí ni Aaroni yóo máa wọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ alufaa rẹ̀, yóo sì máa gbọ́ ìró rẹ̀ nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ lọ níwájú OLUWA ati ìgbà tí ó bá ń jáde, kí ó má baà kú. +“Fi ojúlówó wúrà ṣe ìgbátí kan kí o sì kọ àkọlé sí i gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sí ara òrùka èdìdì, àkọlé náà nìyí: ‘Mímọ́ fún OLUWA.’ +Fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́, aláwọ̀ aró dè é mọ́ fìlà alufaa níwájú. +Nígbà tí Aaroni bá ń rú ẹbọ mímọ́, tí àwọn ọmọ Israẹli ti yà sọ́tọ̀ fún èmi OLUWA, kinní bí àwo pẹrẹsẹ yìí yóo máa wà níwájú orí rẹ̀, kí wọ́n lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ mi. +“Fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tí wọ́n ���e iṣẹ́ ọnà sí dá ẹ̀wù fún Aaroni, kí o fi aṣọ ọ̀gbọ̀ rán fìlà rẹ̀ pẹlu, lẹ́yìn náà rán àmùrè tí a ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára fún un. +Àwọn aṣọ tí wọn yóo rán náà nìwọ̀nyí; ọ̀kan fún ìgbàyà, ati ẹ̀wù efodu, ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ kan, ati ẹ̀wù àwọ̀lékè kan tí a ṣe iṣẹ́ ọnà sí; fìlà kan, ati àmùrè. Wọn yóo rán àwọn aṣọ mímọ́ náà fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi. +“Rán ẹ̀wù ati àmùrè, ati fìlà fún àwọn ọmọ Aaroni fún ògo ati ẹwà. +Gbé àwọn ẹ̀wù náà wọ Aaroni arakunrin rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì ta òróró sí wọn lórí láti yà wọ́n sọ́tọ̀ ati láti yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi. +Fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dá ṣòkòtò fún wọn; láti máa fi bo ìhòòhò wọn, láti ìbàdí títí dé itan. +Kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ máa wọ ṣòkòtò náà, nígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ, tabi nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe iṣẹ́ alufaa ni ibi mímọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n sì kú. Títí laelae ni òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa pa ìlànà yìí mọ́. +Wọn yóo gba wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. +“Wọn yóo ṣe efodu wúrà, ati aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́; wọn yóo sì ṣe iṣẹ́ ọnà sí i lára. +Kí wọ́n rán àgbékọ́ meji mọ́ etí rẹ̀ mejeeji, tí wọn yóo fi lè máa so ó pọ̀. +Irú aṣọ kan náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ni kí wọ́n fi ṣe àmùrè rẹ̀. Iṣẹ́ ọnà kan náà ni kí wọ́n ṣe sí i lára pẹlu wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. +Mú òkúta onikisi meji, kí o sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli sí ara wọn. +Ẹ̀wù Àwọn Alufaa. +“Ohun tí o óo ṣe láti ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sọ́tọ̀ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi nìyí: mú ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan, ati àgbò meji tí kò ní àbùkù, +“Lẹ́yìn náà, mú akọ mààlúù náà wá siwaju àgọ́ àjọ, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé akọ mààlúù náà lórí. +Lẹ́yìn náà, pa akọ mààlúù náà níwájú OLUWA lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ àjọ. +Gbà ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, kí o fi ìka rẹ tọ́ ọ sí ara ìwo pẹpẹ, kí o sì da ìyókù rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. +Fá gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun, ati ẹ̀dọ̀ akọ mààlúù náà; mú kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, ati ọ̀rá tí ó bò wọ́n; kí o sun wọ́n lórí pẹpẹ náà. +Ṣugbọn lẹ́yìn ibùdó ni kí o ti fi iná sun ẹran ara rẹ̀, ati awọ rẹ̀, ati nǹkan inú rẹ̀, nítorí pé, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. +“Lẹ́yìn náà, mú ọ̀kan ninu àwọn àgbò mejeeji, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé e lórí. +Lẹ́yìn náà, pa àgbò náà, sì gba ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o dà á sí ara pẹpẹ yíká. +Gé ẹran àgbò náà sí wẹ́wẹ́, kí o fọ àwọn nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀. Dà wọ́n mọ́ àwọn tí o gé wẹ́wẹ́ ati orí rẹ̀, +kí o sì sun gbogbo wọn lórí pẹpẹ, ẹbọ sísun olóòórùn dídùn ni sí OLUWA, àní ẹbọ tí a fi iná sun. +“Lẹ́yìn náà, mú àgbò keji, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé e lórí. +mú burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, ati àkàrà dídùn tí kò ní ìwúkàrà tí a fi òróró pò, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà, tí a da òróró sí lórí. Ìyẹ̀fun kíkúnná ni kí o fi ṣe wọ́n. +Pa àgbò náà, kí o sì gbà ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kí o tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀, ati sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ati sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn pẹlu. Lẹ́yìn náà, da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ara pẹpẹ yíká. +Mú lára ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lára pẹpẹ, sì mú ninu òróró tí wọ́n máa ń ta sí ni lórí, kí o wọ́n ọn sí Aaroni lórí ati sí ara ẹ̀wù rẹ̀, ati sí orí àwọn ọmọ rẹ̀, ati sí ara ẹ̀wù wọn. Òun ati ẹ̀wù rẹ̀ yóo di mímọ́, àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹ̀wù wọn yóo sì di mímọ́ pẹlu. +“Mú ọ̀rá àgbò náà ati ìrù rẹ̀ tòun tọ̀rá rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun ati èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀; ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n ati itan rẹ̀ ọ̀tún, nítorí àgbò ìyàsímímọ́ ni. +Mú burẹdi kan, àkàrà dídùn kan pẹlu òróró, ati burẹdi pẹlẹbẹ láti inú agbọ̀n burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, tí ó wà níwájú OLUWA. +Kó gbogbo wọn lé Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú OLUWA. +Lẹ́yìn náà, gba gbogbo àkàrà náà lọ́wọ́ wọn, kí o fi iná sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹlu ẹbọ sísun olóòórùn dídùn níwájú OLUWA, ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA ni. +“Mú igẹ̀ àgbò tí a fi ya Aaroni sí mímọ́, kí o sì fì í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, èyí ni yóo jẹ́ ìpín tìrẹ. +“O óo ya igẹ̀ ẹbọ fífì náà sí mímọ́ ati itan tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa lára àgbò ìyàsímímọ́, nítorí pé, ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni. +Yóo máa jẹ́ ìpín ìran wọn títí lae, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣe máa fún àwọn alufaa lára ẹbọ alaafia wọn; ẹbọ wọn sí OLUWA ni. +“Ẹ̀wù mímọ́ Aaroni yóo di ti arọmọdọmọ rẹ̀ lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn aṣọ mímọ́ náà ni wọn yóo máa wọ̀; wọn yóo máa wọ̀ wọ́n nígbà tí wọ́n bá fi àmì òróró yàn wọ́n, tí wọ́n sì yà wọ́n sí mímọ́. +Kó àwọn burẹdi ati àkàrà náà sinu agbọ̀n kan, gbé wọn wá pẹlu akọ mààlúù ati àgbò mejeeji náà. +Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó bá di alufaa dípò rẹ̀ yóo wọ àwọn aṣọ wọnyi fún ọjọ́ meje, nígbà tí ó bá wá sí ibi àgọ́ àjọ. +“Mú àgbò ìyàsímímọ́ náà, kí o sì bọ ẹran ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan. +Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo sì jẹ ẹran àgbò náà, ati burẹdi tí ó wà ninu agbọ̀n, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ. +Wọn yóo jẹ àwọn nǹkan tí wọ́n fi ṣe ètùtù láti yà wọ́n sọ́tọ̀ ati láti yà wọ́n sí mímọ́, eniyan tí kì í bá ṣe alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ninu rẹ̀, nítorí pé mímọ́ ni wọ́n. +Bí ẹran ìyàsímímọ́ ati burẹdi náà bá kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, fi iná sun ìyókù, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ nítorí pé mímọ́ ni. +“Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe sí Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni kí o fi yà wọ́n sí mímọ́. +Lojoojumọ ni kí o máa fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètùtù. O sì níláti máa rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún pẹpẹ náà nígbà tí o bá ń ṣe ètùtù fún un, ta òróró sí i láti yà á sí mímọ́. +Ọjọ́ meje ni o níláti fi ṣe ètùtù fún pẹpẹ, kí o sì yà á sí mímọ́, nígbà náà ni pẹpẹ náà yóo di mímọ́, ohunkohun tí ó bá sì kan pẹpẹ náà yóo di mímọ́ pẹlu. +“Ohun tí o óo máa fi rú ẹbọ lórí pẹpẹ lojoojumọ ni: ọ̀dọ́ aguntan meji, tí ó jẹ́ ọlọ́dún kan. +Fi ọ̀dọ́ aguntan kan rúbọ ní òwúrọ̀, sì fi ekeji rúbọ ní àṣáálẹ́. +“Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n. +Ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a pò pọ̀ mọ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ojúlówó epo olifi, ni kí o fi rúbọ pẹlu àgbò kinni, pẹlu idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ìtasílẹ̀. +Àṣaálẹ́ ni kí o fi ọ̀dọ́ aguntan keji rúbọ, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ọtí waini fún ìtasílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti òwúrọ̀. Ẹbọ olóòórùn dídùn ni, àní ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA. +Atọmọdọmọ yín yóo máa rúbọ sísun náà nígbà gbogbo lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ àjọ, níwájú OLUWA, níbi tí n óo ti máa bá yín pàdé, tí n óo sì ti máa bá yín sọ̀rọ̀. +Ibẹ̀ ni n óo ti máa bá àwọn eniyan Israẹli pàdé, ògo mi yóo sì máa ya ibẹ̀ sí mímọ́. +N óo ya àgọ́ àjọ ati pẹpẹ náà sí mímọ́, ati Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu, kí wọ́n lè máa sìn mí gẹ́gẹ́ bí alufaa. +N óo máa wà láàrin àwọn eniyan Israẹli, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn. +Wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, kí n lè máa gbé ààrin wọn. Èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn. +Lẹ́yìn náà, kó àwọn aṣọ náà, wọ Aaroni lẹ́wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ efodu, ati efodu náà, ati ìgbàyà. Lẹ́yìn náà, fi ọ̀já efodu tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí dì í ní àmùrè. +Fi fìlà náà dé e lórí, kí o sì gbé adé mímọ́ lé orí fìlà náà. +Gbé òróró ìyàsọ́tọ̀, kí o dà á lé e lórí láti yà á sọ́tọ̀. +“Kó àwọn ọmọ rẹ̀ wá, kí o sì wọ̀ wọ́n lẹ́wù, +dì wọ́n lámùrè, kí o sì dé wọn ní fìlà. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, atọmọdọmọ wọn yóo sì máa ṣe alufaa mi. +Àwọn Ìlànà fún Ìyàsọ́tọ̀ Aaroni ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀. +Ní ọjọ́ kan, Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, tíí ṣe alufaa ìlú Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn aṣálẹ̀, títí tí ó fi dé òkè Horebu ní Sinai, tíí ṣe òkè Ọlọrun. +Wá, n óo rán ọ sí Farao, kí o lè lọ kó àwọn eniyan mi, àwọn ọmọ Israẹli, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.” +Ṣugbọn Mose dá Ọlọrun lóhùn pé, “Ta ni mo jẹ́, tí n óo fi wá tọ Farao lọ pé mo fẹ́ kó àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti?” +Ọlọrun bá dá a lóhùn pé, “N óo wà pẹlu rẹ, ohun tí yóo sì jẹ́ àmì fún ọ, pé èmi ni mo rán ọ ni pé, nígbà tí o bá ti kó àwọn eniyan náà kúrò ní Ijipti, ẹ óo sin Ọlọrun ní orí òkè yìí.” +Mose tún bi Ọlọrun pé, “Bí mo bá dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Israẹli, tí mo sì wí fún wọn pé, ‘Ọlọrun àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ bí wọ́n bá wá bi mí pé ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni kí n wí fún wọn?” +Ọlọrun dá Mose lóhùn pé, “ÈMI NI ẸNI TÍ MO JẸ́. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘ÈMI NI ni ó rán mi sí yín.’ ” +Ọlọrun tún fi kún un fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu, ni ó rán òun sí wọn. Ó ní orúkọ òun nìyí títí ayérayé, orúkọ yìí ni wọn óo sì máa fi ranti òun láti ìrandíran. +Ó ní, “Lọ kó gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, kí o sì sọ fún wọn pé, èmi OLUWA, Ọlọrun àwọn baba yín, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu, ni ó farahàn ọ́, ati pé, mo ti ń ṣàkíyèsí wọn, mo ti rí ohun tí àwọn ará Ijipti ti ṣe sí wọn. +Mo ṣèlérí pé n óo yọ wọ́n kúrò ninu ìpọ́njú Ijipti. N óo kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Perisi ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin. +“Wọn yóo gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, ìwọ ati àwọn àgbààgbà Israẹli yóo tọ ọba Ijipti lọ, ẹ óo sì wí fún un pé, ‘OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu ti wá bá wa, jọ̀wọ́, jẹ́ kí á lọ sinu aṣálẹ̀, ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta, kí á lè rúbọ sí OLUWA, Ọlọrun wa.’ +Mo mọ̀ pé ọba Ijipti kò ní jẹ́ kí ẹ lọ rárá, àfi bí mo bá fi ọwọ́ líle mú un. +Angẹli OLUWA farahàn án ninu ahọ́n iná láàrin ìgbẹ́; bí ó ti wò ó, ó rí i pé iná ń jó nítòótọ́, ṣugbọn igbó náà kò jóná. +Nítorí náà n óo lo agbára mi láti fi jẹ Ijipti níyà, ń óo sì ṣe iṣẹ́ ìyanu níbẹ̀, nígbà náà ni yóo tó gbà pé kí ẹ máa lọ. +“N óo jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi rí ojurere àwọn ará Ijipti, nígbà tí ẹ bá ń lọ, ẹ kò ní lọ lọ́wọ́ òfo, +olukuluku obinrin yóo lọ sí ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀ tí ó jẹ́ ará Ijipti ati àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóo tọrọ aṣọ ati ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati ti fadaka, ẹ óo sì fi wọ àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo sì ṣe gba gbogbo ìṣúra àwọn ará Ijipti lọ́wọ́ wọn.” +Mose bá wí ninu ara rẹ̀ pé, “N óo súnmọ́ kinní yìí, mo fẹ́ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná fi ń jó tí igbó kò sì fi jóná.” +Nígbà tí Ọlọrun rí i pé ó súnmọ́ ọn láti wo ohun ìyanu náà, Ọlọrun pè é láti inú igbó náà, ó ní, “Mose! Mose!”Mose dáhùn pé, “Èmi nìyí.” +Ọlọrun ní, “Má ṣe súnmọ́ tòsí ibí, bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé, ilẹ̀ tí o dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” +Ọlọrun tún fi kún un pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu.” Mose bá bo ojú rẹ̀ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á láti wo Ọlọrun. +Lẹ́yìn náà OLUWA dáhùn pé, “Mo ti rí ìpọ́njú àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní Ijipti, mo sì ti gbọ́ igbe wọn, nítorí ìnilára àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́, mo mọ irú ìyà tí wọn ń jẹ, +mo sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti wá gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati láti kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dára, tí ó sì tẹ́jú, ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú tí ó kún fún wàrà ati oyin, àní, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Perisi, ati ti àwọn ará Hifi ati ti àwọn ará Jebusi. +Igbe àwọn eniyan Israẹli ti gòkè tọ̀ mí wá, mo sì ti rí bí àwọn ará Ijipti ṣe ń ni wọ́n lára. +Ọlọrun Pe Mose. +“Fi igi akasia tẹ́ pẹpẹ kan, tí wọn yóo máa sun turari lórí rẹ̀. +Aaroni yóo máa ṣe ètùtù lórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo máa fi ṣe ètùtù náà lórí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ní ìrandíran yín. Pẹpẹ náà yóo jẹ́ ohun èlò tí ó mọ́ jùlọ fún OLUWA.” +OLUWA sọ fún Mose pé, +“Nígbà tí o bá ka iye àwọn eniyan Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ mú ohun ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ wá fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn, nígbà tí o bá kà wọ́n. +Ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí o bá kà yóo san ni: ìdajì ṣekeli, tí a fi ìwọ̀n ilé OLUWA wọ̀n, (tí ó jẹ́ ogún ìwọ̀n gera fún ìwọ̀n ṣekeli kan), ìdajì ṣekeli náà yóo sì jẹ́ ti OLUWA. +Ẹnikẹ́ni tí a bá kà ní àkókò ìkànìyàn náà, tí ó bá tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó gbọdọ̀ san owó náà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA. +Bí eniyan ti wù kí ó ní owó tó, kò gbọdọ̀ san ju ìdajì ṣekeli kan lọ; bí ó sì ti wù kí eniyan tòṣì tó, kò gbọdọ̀ san dín ní ìdajì ṣekeli kan, nígbà tí ẹ bá ń san ọrẹ OLUWA fún ìràpadà ẹ̀mí yín. +Gba owó ètùtù lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli, kí o sì máa lò ó fún iṣẹ́ ilé ìsìn àgọ́ àjọ, kí ó lè máa mú àwọn ọmọ Israẹli wá sí ìrántí níwájú OLUWA, kí ó sì lè jẹ́ ètùtù fún yín.” +OLUWA tún wí fún Mose pé, +“Fi idẹ ṣe agbada omi kan, kí ìdí rẹ̀ náà jẹ́ idẹ, gbé e sí ààrin àgọ́ àjọ ati pẹpẹ, kí o sì bu omi sinu rẹ̀. +Omi yìí ni Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo fi máa fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn. +Kí gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, fífẹ̀ rẹ̀ yóo sì jẹ́ igbọnwọ kan. Ìbú ati òòró rẹ̀ yóo rí bákan náà, yóo sì ga ní igbọnwọ meji, àṣepọ̀ mọ́ ìwo rẹ̀ ni kí o ṣe é. +Nígbà tí wọ́n bá ń wọ àgọ́ àjọ lọ, tabi nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe iṣẹ́ alufaa wọn, láti rú ẹbọ sísun sí OLUWA; omi yìí ni wọ́n gbọdọ̀ fi fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn kí wọ́n má baà kú. +Dandan ni kí wọ́n fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n má baà kú. Èyí yóo di ìlànà fún wọn títí lae: fún òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ ní gbogbo ìran wọn.” +Lẹ́yìn náà, OLUWA tún wí fún Mose pé, +“Mú ojúlówó àwọn nǹkan olóòórùn dídùn wọnyi kí o kó wọn jọ: ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli òjíá olómi, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli sinamoni, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli igi olóòórùn dídùn kan tí ó dàbí èèsún, +ati ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli kasia, ìwọ̀n ṣekeli ilé OLUWA ni kí wọ́n lò láti wọ̀n wọ́n. Lẹ́yìn náà, mú ìwọ̀n hini ojúlówó òróró olifi kan. +Pa gbogbo nǹkan wọnyi pọ̀, kí o fi ṣe òróró mímọ́ fún ìyàsímímọ́. Ṣe é bí àwọn ìpara olóòórùn dídùn, yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ fún OLUWA. +Ta òróró yìí sí ara àgọ́ àjọ, ati sí ara àpótí ẹ̀rí, +ati sí ara tabili, ati gbogbo àwọn ohun èlò orí rẹ̀, ati sí ara ọ̀pá fìtílà ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati sí ara pẹpẹ turari, +ati sí ara pẹpẹ ẹbọ sísun, ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati sí ara agbada omi, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. +Fi yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè jẹ́ mímọ́ patapata; ohunkohun tí ó bá kàn wọ́n yóo sì di mímọ́. +Fi ojúlówó wúrà bo òkè, ati gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, ati ìwo rẹ̀ pẹlu. Fi wúrà ṣe ìgbátí yí gbogbo etí rẹ̀ po. +Ta òróró yìí sí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lórí, kí o fi yà wọ́n sí mímọ́; kí wọ́n lè máa ṣe alufaa fún mi. +Sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Òróró yìí ni yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ ní ìrandíran yín, +ẹ kò gbọdọ̀ dà á sí ara àwọn eniyan lásán, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe òróró mìíràn tí ó dàbí rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́. +Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe irú rẹ̀, tabi ẹnikẹ́ni tí ó bá dà á sórí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe alufaa, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.’ ” +OLUWA wí fún Mose pé, “Mú àwọn ohun ìkunra olóòórùn dídùn wọnyi: sitakite, ati onika, ati galibanumi ati ojúlówó turari olóòórùn dídùn, gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà. +Lọ̀ wọ́n pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn tí wọn ń ṣe turari, kí o fi iyọ̀ sí i; yóo sì jẹ́ mímọ́. +Bù ninu rẹ̀, kí o gún un lúbúlúbú. Lẹ́yìn náà, bù díẹ̀ ninu lúbúlúbú yìí, kí o fi siwaju àpótí ẹ̀rí ninu àgọ́ àjọ, níbi tí n óo ti bá ọ pàdé, yóo jẹ́ mímọ́ fún yín. +Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe irú turari náà fún ara yín, ṣugbọn ẹ mú un gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA. +Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe irú rẹ̀, láti máa lò ó gẹ́gẹ́ bíi turari, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.” +Lẹ́yìn náà, ṣe òrùka wúrà meji fún pẹpẹ náà, jó wọn mọ́ abẹ́ ìgbátí r��̣ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àwọn òrùka náà ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé pẹpẹ náà. +Fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n. +Gbé e sílẹ̀ lóde aṣọ títa tí ó wà lẹ́bàá àpótí ẹ̀rí, lọ́gangan iwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lókè àpótí ẹ̀rí náà, níbi tí n óo ti máa ba yín pàdé. +Kí Aaroni máa sun turari olóòórùn dídùn lórí rẹ̀, ní àràárọ̀, nígbà tí ó bá ń tọ́jú àwọn fìtílà. +Nígbà tí ó bá ń gbé àwọn fìtílà náà sí ààyè wọn ní àṣáálẹ́, yóo máa sun turari náà pẹlu, títí lae ni yóo máa sun turari náà níwájú OLUWA ní ìrandíran yín. +Ẹ kò gbọdọ̀ sun turari tí ó jẹ́ aláìmọ́ lórí pẹpẹ náà, ẹ kò sì gbọdọ̀ sun ẹbọ sísun lórí rẹ̀; tabi ẹbọ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ta ohun mímu sílẹ̀ fún ètùtù lórí rẹ̀. +Pẹpẹ fún Sísun Turari. +OLUWA sọ fún Mose pé, +ati àwọn ẹ̀wù tí a dárà sí, ẹ̀wù mímọ́ Aaroni alufaa ati ẹ̀wù àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa wọn, +ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ patapata ni wọn yóo ṣe bí mo ti pa á láṣẹ.” +OLUWA rán Mose, ó ní, +“Sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, nítorí pé òun ni àmì tí ó wà láàrin èmi pẹlu yín ní ìrandíran yín; kí ẹ lè mọ̀ pé, èmi OLUWA yà yín sọ́tọ̀ fún ara mi. +Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ di aláìmọ́, pípa ni kí wọ́n pa á; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀. +Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, èyí tí ó jẹ́ mímọ́ fún OLUWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ ìsinmi, pípa ni kí wọ́n pa á. +Nítorí náà, àwọn eniyan Israẹli yóo máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, wọn yóo máa ranti rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì majẹmu ní ìrandíran wọn. +Ọjọ́ náà jẹ́ àmì ayérayé tí ó wà láàrin èmi ati àwọn eniyan Israẹli, pé ọjọ́ mẹfa ni èmi Ọlọrun fi dá ọ̀run ati ayé, ati pé ní ọjọ́ keje, mo dáwọ́ iṣẹ́ ṣíṣe dúró, mo sì sinmi.’ ” +Nígbà tí Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀ tán lórí òkè Sinai, ó fún un ní wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí. Ọlọrun fúnra rẹ̀ ni ó fi ìka ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára àwọn wàláà náà. +“Wò ó, mo ti pe Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, láti inú ẹ̀yà Juda. +Mo sì ti fi ẹ̀mí Ọlọrun kún inú rẹ̀, mo ti fún un ní òye ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ iṣẹ́ ọnà, +láti fi wúrà ati fadaka ati idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà, +láti dá oríṣìíríṣìí àrà sí ara òkúta ati láti tò ó, láti gbẹ́ igi ati láti fi oríṣìíríṣìí ohun èlò ṣe iṣẹ́ ọnà. +Mo ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani pẹlu rẹ̀. Mo sì ti fún gbogbo àwọn oníṣẹ́ ọnà ní ọgbọ́n, kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ. +Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ lórí àgọ́ àjọ, ati àpótí ẹ̀rí ati ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, ati gbogbo àwọn ohun èlò àgọ́, +ati tabili, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, pẹpẹ turari, +pẹpẹ ẹbọ sísun ati gbogbo ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀ ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀; +Àwọn Òṣìṣẹ́ fún Àgọ́ OLUWA. +Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i pé Mose ń pẹ́ jù lórí òkè, wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n tọ Aaroni lọ; wọ́n sọ fún un pé, “Ṣe oriṣa kan fún wa, tí yóo máa ṣáájú wa lọ; nítorí pé, a kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.” +Dá mi dá wọn, inú ń bí mi sí wọn gidigidi, píparẹ́ ni n óo sì pa wọ́n rẹ́, ṣugbọn n óo sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá.” +Ṣugbọn Mose bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kí ló dé tí inú fi bí ọ tóbẹ́ẹ̀ sí àwọn eniyan rẹ, àwọn tí o fi agbára ati tipátipá kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti? +Kí ló dé tí o óo fi jẹ́ kí àwọn ará Ijipti wí pé, o mọ̀ọ́nmọ̀ fẹ́ ṣe wọ́n níbi ni o fi kó wọn jáde láti pa wọ́n lórí òkè yìí, ati láti pa wọ́n rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé? Jọ̀wọ́, má bínú mọ, yí ọkàn rẹ pada, má sì ṣe ibi tí o ti pinnu láti ṣe sí àwọn eniyan rẹ. +Wo ti Abrahamu, ati Isaaki, ati Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ, àwọn tí o ti fi ara rẹ búra fún pé o ó sọ arọmọdọmọ wọn di pupọ gẹ́gẹ́ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run; o ní gbogbo ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí ni o óo fi fún àwọn arọmọdọmọ wọn; ati pé àwọn ni wọn yóo sì jogún rẹ̀ títí lae.” +Ọlọrun bá yí ọkàn rẹ̀ pada, kò sì ṣe ibi tí ó gbèrò láti ṣe sí àwọn eniyan náà mọ́. +Mose bá yipada, ó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, tòun ti wàláà òkúta ẹ̀rí mejeeji lọ́wọ́ rẹ̀, àwọn wàláà òkúta tí Ọlọrun ti kọ nǹkan sí lójú mejeeji. +Iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọrun ni àwọn wàláà òkúta náà, Ọlọrun tìkararẹ̀ ni ó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára wọn. +Bí Joṣua ti gbọ́ ariwo àwọn eniyan náà tí wọn ń ké, ó wí fún Mose pé, “Ariwo ogun wà ninu àgọ́.” +Ṣugbọn Mose dáhùn pé, “Èyí kì í ṣe ìhó ìṣẹ́gun, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe igbe ẹni tí wọ́n ṣẹgun rẹ̀, ìró orin ni èyí tí mò ń gbọ́ yìí.” +Bí ó ti súnmọ́ tòsí àgọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó rí ère ọmọ mààlúù, ó sì rí àwọn eniyan tí wọn ń jó. Inú bí Mose gidigidi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ju àwọn wàláà òkúta náà mọ́lẹ̀, ó sì fọ́ wọn ní ẹsẹ̀ òkè náà. +Aaroni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gba gbogbo yẹtí wúrà etí àwọn aya yín jọ, ati ti àwọn ọmọkunrin yín, ati ti àwọn ọmọbinrin yín, kí ẹ sì kó wọn wá.” +Ó mú ère ọmọ mààlúù náà, tí wọ́n fi wúrà ṣe, ó sun ún níná, ó lọ̀ ọ́ lúbúlúbú, ó kù ú sójú omi, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Israẹli mu. +Mose bi Aaroni pé, “Kí ni àwọn eniyan wọnyi fi ṣe ọ́, tí o fi mú ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá yìí wá sórí wọn?” +Aaroni bá dáhùn, ó ní, “Má bínú, oluwa mi, ṣebí ìwọ náà mọ àwọn eniyan wọnyi pé eeyankeeyan ni wọ́n, +àwọn ni wọ́n wá bá mi tí wọ́n ní, ‘Ṣe oriṣa fún wa tí yóo máa ṣáájú wa lọ, nítorí pé a kò mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Mose, tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.’ +Ni mo bá wí fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Wọ́n kó wọn fún mi, ni mo bá dà wọ́n sinu iná, òun ni mo sì fi yá ère mààlúù yìí.” +Nígbà tí Mose rí i pé Aaroni ti dá rúdurùdu sílẹ̀, láàrin àwọn eniyan náà, ati pé apá kò ká wọn mọ́, ọ̀rọ̀ náà sì sọ wọ́n di ẹni ìtìjú níwájú àwọn ọ̀tá wọn, +Mose bá dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó ní, “Ẹ̀yin wo ni ẹ̀ ń ṣe ti OLUWA, ẹ máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ọmọ Lefi bá kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. +Mose wí fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ bí OLUWA Ọlọrun Israẹli ti wí, ó ní, ‘Gbogbo ẹ̀yin ọkunrin, ẹ sán idà yín mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín kí ẹ sì máa lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, jákèjádò ibùdó, kí olukuluku máa pa arakunrin rẹ̀ ati ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ati aládùúgbò rẹ̀.’ ” +Àwọn ọmọ Lefi sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí, àwọn tí wọ́n kú láàrin àwọn eniyan náà tó ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin. +Mose bá wí fún wọn pé, “Lónìí ni ẹ yan ara yín fún iṣẹ́ OLUWA, olukuluku yín sì ti fi ẹ̀mí ọmọ rẹ̀, ati ti arakunrin rẹ̀ yan ara rẹ̀, kí ó lè tú ibukun rẹ̀ sí orí yín lónìí yìí.” +Gbogbo àwọn eniyan náà bá bọ́ yẹtí wúrà etí wọn jọ, wọ́n kó wọn tọ Aaroni lọ. +Ní ọjọ́ keji, Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá, n óo tún gòkè tọ OLUWA lọ, bóyá n óo lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.” +Mose bá pada tọ OLUWA lọ, ó ní, “Yéè! Àwọn eniyan wọnyi ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá; wọ́n ti fi wúrà yá ère fún ara wọn; +ṣugbọn OLUWA, jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, pa orúkọ mi rẹ́ patapata kúrò ninu ìwé tí o kọ orúkọ àwọn eniyan rẹ sí.” +OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi ni n óo pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò ninu ìwé mi. +Pada lọ nisinsinyii, kí o sì kó àwọn eniyan náà lọ sí ibi tí mo sọ fún ọ. Ranti pé angẹli mi yóo máa ṣáájú yín lọ, ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo jẹ àwọn eniyan náà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” +Nítorí náà, nígbà tó yá, Ọlọrun rán àjàkálẹ̀ àrùn burúkú kan sáàrin àwọn eniyan náà, nítorí pé wọ́n mú kí Aaroni fi wúrà yá ère mààlúù fún wọn. +Aaroni gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn, ó lo irinṣẹ́ àwọn alágbẹ̀dẹ, ó fi wúrà náà da ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan. Àwọn eniyan náà bá dáhùn pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ọlọrun yín tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìyí.” +Nígbà tí Aaroni rí i bẹ́ẹ̀, ó tẹ́ pẹpẹ kan siwaju ère náà, ó sì kéde pé, “Ọ̀la yóo jẹ́ ọjọ́ àjọ fún OLUWA.” +Wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, wọ́n rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ alaafia wá, wọ́n bá jókòó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń ṣe àríyá tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn lòpọ̀. +OLUWA wí fún Mose pé, “Tètè sọ̀kalẹ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ tí o kó ti ilẹ̀ Ijipti wá ti ba ara wọn jẹ́. +Wọ́n ti yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ti yá ère mààlúù kan, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí bọ ọ́, wọ́n sì ti ń rúbọ sí i. Wọ́n ń wí pé, ‘ọlọ́run yín nìyí Israẹli, ẹni tí ó mú yín gòkè wá láti ilẹ̀ Ijipti.’ ” +OLUWA bá wí fún Mose pé, “Mo ti rí àwọn eniyan wọnyi, wò ó, alágídí ni wọ́n. +Ère Mààlúù Wúrà. +OLUWA tún pe Mose, ó ní, “Dìde kúrò níhìn-ín, ìwọ ati àwọn eniyan tí o kó wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ lọ sí ilẹ̀ tí mo ti búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé n óo fún arọmọdọmọ wọn. +Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan bá sì rí ìkùukùu tí ó dàbí òpó yìí, lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, gbogbo àwọn eniyan á dìde, olukuluku wọn á sì sin OLUWA ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀. +Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ ní ojúkoojú, bí eniyan ṣe ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà tí Mose bá pada sí ibùdó, Joṣua, iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, tí òun jẹ́ ọdọmọkunrin, kìí kúrò ninu àgọ́ àjọ. +Mose bá wí fún OLUWA pé, “Ṣebí ìwọ OLUWA ni o sọ pé kí n kó àwọn eniyan wọnyi wá, ṣugbọn o kò tíì fi ẹni tí o óo rán ṣìkejì mi hàn mí. Sibẹsibẹ, o wí pé, o mọ̀ mí o sì mọ orúkọ mi, ati pé mo ti rí ojurere rẹ. +Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́, bí inú rẹ bá dùn sí mi, fi ọ̀nà rẹ hàn mí, kí n lè mọ̀ ọ́, kí ǹ sì lè bá ojurere rẹ pàdé. Sì ranti pé àwọn eniyan rẹ ni àwọn eniyan wọnyi.” +OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Ojú mi yóo máa bá ọ lọ, n óo sì fún ọ ní ìsinmi.” +Mose wí fún OLUWA pé, “Bí o kò bá ní bá wa lọ, má wulẹ̀ kó wa kúrò níhìn-ín. +Nítorí pé, báwo ni àwọn eniyan yóo ṣe mọ̀ pé, inú rẹ dùn sí èmi ati àwọn eniyan rẹ? Ṣebí bí o bá wà pẹlu wa bí a ti ń lọ ni a óo fi lè dá èmi ati àwọn eniyan rẹ mọ̀ yàtọ̀ sí gbogbo aráyé yòókù.” +OLUWA dá Mose lóhùn pé, “N óo ṣe ohun tí o wí, nítorí pé inú mi dùn sí ọ, mo sì mọ orúkọ rẹ.” +Mose dáhùn pé, “Mo bẹ̀ ọ́, fi ògo rẹ hàn mí.” +OLUWA sì dá Mose lóhùn pé, “N óo mú kí ẹwà mi kọjá níwájú rẹ; n óo sì pe orúkọ mímọ́ mi lójú rẹ, èmi ni OLUWA, èmi a máa yọ́nú sí àwọn tí ó bá wù mí, èmi a sì máa ṣàánú fún àwọn tí mo bá fẹ́.” +N óo rán angẹli mi ṣáájú yín, n óo sì lé àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hamori, àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi jáde. +OLUWA ní, “O kò lè rí ojú mi nítorí pé eniyan kò lè rí ojú mi kí ó wà láàyè.” +OLUWA tún dáhùn pé, “Ibìkan wà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, wá dúró lórí òkúta kan níbẹ̀. +Nígbà tí ògo mi bá ń kọjá lọ, n óo pa ọ́ mọ́ ninu ihò òkúta yìí, n óo sì fi ọwọ́ mi bò ọ́ lójú nígbà tí mo bá ń rékọjá. +Lẹ́yìn náà, n óo ká ọwọ́ mi kúrò, o óo sì rí àkẹ̀yìnsí mi, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè rí ojú mi.” +Ẹ lọ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá náà, tí ó kún fún wàrà ati oyin; n kò ní sí ní ààrin yín nígbà tí ẹ bá ń lọ, nítorí orí kunkun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ n óo pa yín run lójú ọ̀nà.” +Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́ ìròyìn burúkú náà, ọkàn wọn bàjẹ́, kò sì sí ẹni tí ó fi ohun ọ̀ṣọ́ sí ara rárá. +Nítorí náà, OLUWA rán Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé olóríkunkun ni wọ́n, ati pé bí òun bá sọ̀kalẹ̀ sí ààrin wọn ní ìṣẹ́jú kan, òun yóo pa wọ́n run; nítorí náà, kí wọ́n kó gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò, kí òun lè mọ ohun tí òun yóo fi wọ́n ṣe. +Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli bọ́ gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò, ní òkè Horebu. +Mose a máa pa àgọ́ àjọ sí òkèèrè, lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli, ó sì sọ ọ́ ní àgọ́ àjọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ní ohunkohun láti bèèrè lọ́dọ̀ OLUWA yóo lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà, tí ó wà lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli. +Nígbàkúùgbà tí Mose bá ń lọ sí ibi àgọ́ àjọ, olukuluku á dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, wọn a sì máa wò ó títí yóo fi wọ inú àgọ́ àjọ lọ. +Bí Mose bá ti wọ inú àgọ́ àjọ náà lọ, ìkùukùu náà á sọ̀kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpó, a sì dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ náà. OLUWA yóo sì bá Mose sọ̀rọ̀. +OLUWA Pàṣẹ Pé Kí Àwọn Eniyan Israẹli Kúrò ní Òkè Sinai. +Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Gbẹ́ wàláà òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, n óo sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí mo kọ sára wàláà ti àkọ́kọ́ tí ó fọ́ sára wọn. +OLUWA wí fún Mose pé, “Mo dá majẹmu kan, n óo ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú àwọn eniyan náà, irú èyí tí ẹnikẹ́ni kò rí rí ní gbogbo ayé tabi láàrin orílẹ̀-èdè kankan. Gbogbo àwọn eniyan tí ẹ̀ ń gbé ààrin wọn yóo sì rí iṣẹ́ OLUWA, nítorí ohun tí n óo ṣe fún wọn yóo bani lẹ́rù jọjọ. +“Máa pa àwọn òfin tí mo fún ọ lónìí yìí mọ́. N óo lé àwọn ará Hamori ati àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, jáde kúrò níwájú rẹ. +Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ rí i pé ẹ kò bá àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ dá majẹmu kankan, kí wọn má baà dàbí tàkúté tí a dẹ sí ààrin yín. +Ṣugbọn, ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn, kí ẹ sì fọ́ gbogbo àwọn ère wọn, kí ẹ sì gé gbogbo igbó oriṣa wọn lulẹ̀. +“Ẹ kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, nítorí èmi OLUWA, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ owú, Ọlọrun tíí máa jowú ni mí. +Ẹ kò gbọdọ̀ bá ẹnikẹ́ni dá majẹmu ninu gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà, kí ẹ má baà bá wọn dá majẹmu tán, kí ó wá di pé, nígbà tí wọn bá ń rúbọ sí oriṣa wọn, tí wọn sì ń ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn, wọn óo máa pè yín, pé kí ẹ máa lọ bá wọn jẹ ninu ẹbọ wọn. +Kó má baà wá di pé ẹ̀ ń fẹ́mọ lọ́wọ́ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín, kí àwọn ọmọbinrin yín má baà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa, kí wọ́n sì mú kí àwọn ọmọkunrin yín náà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn. +“Ẹ kò gbọdọ̀ yá ère fún ara yín. +“Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe àjọ àìwúkàrà, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ fún ọjọ́ meje ní àkókò àjọ náà, ninu oṣù Abibu, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún yín, nítorí pé ninu oṣù Abibu ni ẹ jáde ní ilẹ̀ Ijipti. +“Tèmi ni gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ àkọ́bí, gbogbo àkọ́bí ẹran: kì báà jẹ́ ti mààlúù, tabi ti aguntan. +Múra ní àárọ̀ ọ̀la, kí o gun òkè Sinai wá, kí o wá farahàn mí lórí òkè náà. +Ṣugbọn ọ̀dọ́ aguntan ni kí ẹ máa fi ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín tí ó bá jẹ́ akọ pada, tí ẹ kò bá fẹ́ rà á pada, ẹ gbọdọ̀ lọ́ ọ lọ́rùn pa. Gbogbo àkọ́bí yín lọkunrin, ni ẹ gbọdọ̀ rà pada. “Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá siwaju mi ní ọwọ́ òfo láti sìn mí. +“Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ fi ṣe iṣẹ́ yín, ní ọjọ́ keje ẹ gbọdọ̀ sinmi; kì báà ṣe àkókò oko ríro, tabi àkókò ìkórè, dandan ni kí ẹ sinmi. +“Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe àjọ̀dún ọ̀sẹ̀ ìkórè àkọ́so alikama ọkà yín, ati àjọ̀dún ìkójọ nígbà tí ẹ bá ń kórè nǹkan oko sinu abà ní òpin ọdún. +“Ẹẹmẹta lọdọọdun, ni gbogbo àwọn ọmọkunrin yín gbọdọ̀ wá siwaju èmi OLUWA Ọlọrun, Ọlọrun Israẹli, kí wọ́n wá sìn mí. +Nítorí pé n óo lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún yín, n óo sì fẹ ààlà yín sẹ́yìn. Kò sì ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo fẹ́ gba ilẹ̀ yín nígbà tí ẹ bá lọ sin OLUWA Ọlọrun yín, lẹẹmẹtẹẹta lọdọọdun. +“Ẹ kò gbọdọ̀ fi ẹran rúbọ sí mi pẹlu ìwúkàrà, bẹ́ẹ̀ ni ohunkohun tí ẹ bá sì fi rú ẹbọ àjọ̀dún ìrékọjá kò gbọdọ̀ kù di ọjọ́ keji. +“Ẹ gbọdọ̀ mú àkọ́so oko yín wá sí ilé OLUWA Ọlọrun yín.“Ẹ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi ọmú ìyá rẹ̀.” +OLUWA wí fún Mose pé, “Kọ ọ̀rọ̀ wọnyi sílẹ̀, nítorí pé òun ni majẹmu mi dúró lé lórí pẹlu ìwọ ati Israẹli.” +Mose sì wà pẹlu OLUWA fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ó sì kọ ọ̀rọ̀ majẹmu náà, tíí ṣe òfin mẹ́wàá, sára àwọn wàláà òkúta náà. +Nígbà tí Mose sọ̀kalẹ̀ pada ti orí òkè Sinai dé, pẹlu wàláà ẹ̀rí meji lọ́wọ́ rẹ̀, Mose kò mọ̀ pé ojú òun ń dán, ó sì ń kọ mànàmànà, nítorí pé ó bá Ọlọrun sọ̀rọ̀. +Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá ọ wá, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ sí níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà, àwọn mààlúù, tabi àwọn aguntan kò gbọdọ̀ jẹ káàkiri níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà.” +Nígbà tí Aaroni, ati àwọn ọmọ Israẹli rí Mose, wọ́n ṣe akiyesi pé ojú rẹ̀ ń kọ mànàmànà, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti súnmọ́ ọn. +Ṣugbọn Mose pè wọ́n, Aaroni ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀. +Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli súnmọ́ ọn, ó sì ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun bá a sọ lórí òkè Sinai lófin fún wọn. +Lẹ́yìn tí Mose bá wọn sọ̀rọ̀ tán ó fi aṣọ ìbòjú bo ojú rẹ̀. +Ṣugbọn nígbà tí Mose bá wọlé lọ, láti bá OLUWA sọ̀rọ̀, a máa mú aṣọ ìbòjú náà kúrò ní ojú títí yóo fi jáde, nígbà tí ó bá sì jáde, yóo sọ ohun tí OLUWA bá pa láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli. +Àwọn ọmọ Israẹli ṣe akiyesi ojú Mose, pé ó ń kọ mànàmànà; Mose a sì máa fi aṣọ ìbòjú bo ojú rẹ̀ títí yóo fi di ìgbà tí yóo tún wọ ilé lọ láti bá OLUWA sọ̀rọ̀. +Mose bá gbẹ́ wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bíi ti àkọ́kọ́, ó gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gun òkè Sinai lọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un; ó kó àwọn wàláà òkúta mejeeji náà lọ́wọ́. +OLUWA tún sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu ó dúró níbẹ̀ pẹlu rẹ̀, ó sì pe orúkọ mímọ́ ara rẹ̀. +OLUWA kọjá níwájú rẹ̀, ó sì kéde orúkọ ara rẹ̀ báyìí pé, “OLUWA Ọlọrun aláàánú ati olóore, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ ní àánú ati òtítọ́. +Ẹni tí ó máa ń ṣàánú fún ẹgbẹẹgbẹrun, tí ó máa ń dárí àìṣedéédé ji eniyan, ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀, ati ìrékọjá jì, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà, a sì máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.” +Mose yára tẹ orí ba, ó dojú bolẹ̀, ó sì sin OLUWA. +Ó ní, “Bí inú rẹ bá dùn sí mi nítòótọ́, OLUWA, jọ̀wọ́, máa wà láàrin wa, nígbà tí a bá ń lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olóríkunkun ni àwọn eniyan náà; dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé wa jì wá, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí eniyan rẹ.” +Àwọn Wàláà Òkúta Keji. +Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ pé kí ẹ máa ṣe nìwọ̀nyí: +“Kí gbogbo ọkunrin tí ó bá mọ iṣẹ́ ọwọ́ ninu yín jáde wá láti ṣe àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ wọnyi: +àgọ́ àjọ, ati àwọn ìbòrí rẹ, àwọn ìkọ́ rẹ̀ ati àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn. +Àpótí ẹ̀rí, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀, ìtẹ́ àánú rẹ̀, ati aṣọ títa rẹ̀. +Tabili, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ pẹlu burẹdi ìfihàn orí rẹ̀. +Ọ̀pá fìtílà fún iná títàn, ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ fìtílà rẹ̀ ati òróró fún iná títàn. +Pẹpẹ turari, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn, ati àwọn aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà. +Pẹpẹ ẹbọ sísun tòun ti ojú ààrò onídẹ rẹ̀, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ ẹbọ, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. +Àwọn aṣọ títa ti àgbàlá ati àwọn òpó rẹ̀ ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. +Àwọn èèkàn àgọ́, ati àwọn èèkàn àgbàlá pẹlu àwọn okùn wọn; +àwọn aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa níbi mímọ́, ati àwọn ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa, ati ẹ̀wù iṣẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa.” +Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn kí ẹ ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ fún OLUWA bí ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà, pípa ni kí ẹ pa á. +Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá túká lọ́dọ̀ Mose. +Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà wọ̀ lọ́kàn, tí ó sì jẹ lógún bẹ̀rẹ̀ sí pada wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọn ń mú ọrẹ wá fún kíkọ́ àgọ́ àjọ náà, ati gbogbo ohun tí wọn nílò fún àgọ́ náà, ati fún ẹ̀wù mímọ́ àwọn alufaa. +Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá, atọkunrin atobinrin, gbogbo àwọn tí ó tinú ọkàn wọn wá, wọ́n mú yẹtí wúrà wá, ati òrùka wúrà, ati ẹ̀gbà wúrà, ati oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn tí wọ́n fi wúrà ṣe; olukuluku wọn mú ẹ̀bùn wúrà wá fún OLUWA. +Gbogbo àwọn tí wọ́n ní aṣọ aláwọ̀ aró, tabi ti elése àlùkò, tabi aṣọ pupa, tabi aṣọ funfun, tabi irun ewúrẹ́, tabi awọ àgbò tí a ṣe ní pupa, tabi awọ ewúrẹ́, bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn wá. +Gbogbo àwọn tí wọ́n lè fi fadaka ati idẹ tọrẹ fún OLUWA ni wọ́n mú wọn wá, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn tí wọ́n ní igi akasia, tí ó wúlò náà mú wọn wá pẹlu. +Gbogbo àwọn obinrin tí wọ́n mọ òwú ran ni wọ́n ran òwú tí wọ́n sì kó o wá: àwọn òwú aláwọ̀ aró, elése àlùkò, aláwọ̀ pupa, ati funfun tí wọ́n fi ń hun aṣọ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. +Gbogbo àwọn obinrin tí ọ̀rọ̀ náà jẹ lógún, tí wọ́n sì mọ irun ewúrẹ́ ran, ni wọ́n ran án wá. +Àwọn àgbààgbà mú òkúta onikisi wá ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà, +ati oríṣìíríṣìí èròjà ati òróró ìtànná, ati ti ìyàsímímọ́, ati fún turari olóòórùn dídùn. +Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọkunrin ati lobinrin tí ọ̀rọ̀ náà jẹ lógún ni wọ́n mú ọrẹ àtinúwá wá fún OLUWA, láti fi ṣe iṣẹ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose. +Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dáná ní gbogbo ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi.” +Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “OLUWA fúnra rẹ̀ ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, láti inú ẹ̀yà Juda. +Ọlọrun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ sinu rẹ̀, ó sì ti fún un ní ọgbọ́n, òye, ati ìmọ̀ ninu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà, +láti fi wúrà ati fadaka ati idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà; +láti gé oríṣìíríṣìí òkúta iyebíye ati láti tò wọ́n, bẹ́ẹ̀ náà ni igi gbígbẹ́ ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà ṣíṣe. +Ọlọrun sì ti mí ìmísí rẹ̀ sí i ninu láti kọ́ ẹlòmíràn, àtòun ati Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani. +Ọlọrun ti fún wọn ní ìmọ̀ oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí àwọn oníṣọ̀nà máa ń ṣe, ati ti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati ti àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ, ìbáà jẹ́ aṣọ aláwọ̀ aró, tabi ti elése àlùkò tabi aṣọ pupa tabi aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ tabi oríṣìí aṣọ mìíràn, gbogbo iṣẹ́ ọnà ni wọn yóo máa ṣe; kò sì sí iṣẹ́ ọnà tí wọn kò lè ṣe. +Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA pa láṣẹ, ó ní, +‘Ẹ gba ọrẹ jọ fún OLUWA láàrin ara yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́, lè mú ọrẹ wá fún OLUWA. Àwọn ọrẹ náà ni: wúrà, fadaka ati idẹ, +aṣọ aláwọ̀ aró, ti aláwọ̀ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ati irun ewúrẹ́; +awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní àwọ̀ pupa ati awọ ewúrẹ́, igi akasia, +òróró ìtànná, àwọn èròjà fún òróró ìyàsímímọ́ ati fún turari olóòórùn dídùn, +òkúta onikisi ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà.’ +Àwọn ìlànà fún Ọjọ́ Ìsinmi. +“Kí Besaleli, ati Oholiabu ati olukuluku àwọn tí OLUWA fún ní ìmọ̀ ati òye, láti ṣe èyíkéyìí ninu iṣẹ́ tí ó jẹmọ́ kíkọ́ ilé mímọ́ náà, ṣe é bí OLUWA ti pa á láṣẹ gan-an.” +Ó rán marun-un ninu àwọn aṣọ títa náà pọ̀, ó sì rán marun-un yòókù pọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. +Ó mú aṣọ aláwọ̀ aró, wọ́n fi rán ojóbó sára aṣọ títa tí ó kángun síta ninu àránpọ̀ aṣọ kinni, wọ́n sì tún rán ojóbó sára aṣọ títa tó kángun síta ninu àránpọ̀ aṣọ keji bákan náà. +Aadọta ojóbó ni wọ́n rán mọ́ àránpọ̀ aṣọ títa kinni, aadọta ojóbó náà ni wọ́n sì rán mọ́ etí àránpọ̀ aṣọ títa keji, àwọn ojóbó náà dojú kọ ara wọn. +Wọ́n ṣe aadọta ìkọ́ wúrà, wọ́n fi àwọn ìkọ́ náà kọ́ àránpọ̀ aṣọ títa náà mọ́ ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni àgọ́ náà ṣe di odidi kan. +Wọ́n tún mú aṣọ títa mọkanla tí wọ́n fi irun ewúrẹ́ ṣe, wọ́n rán an pọ̀, wọ́n fi ṣe ìbòrí sí àgọ́ náà. +Gígùn aṣọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin; bákan náà ni òòró ati ìbú àwọn aṣọ mọkọọkanla. +Wọ́n rán marun-un pọ̀ ninu àwọn aṣọ títa náà, lẹ́yìn náà ó rán mẹfa yòókù pọ̀. +Wọ́n ṣe aadọta ojóbó sára èyí tí ó kángun síta lára àránpọ̀ aṣọ kinni, ati èyí tí ó kángun síta lára àránpọ̀ aṣọ keji. +Wọ́n sì ṣe aadọta ìkọ́ idẹ láti fi mú aṣọ àgọ́ náà papọ̀ kí ó lè di ẹyọ kan ṣoṣo. +Wọ́n fi awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní pupa ati awọ ewúrẹ́ ṣe ìbòrí àgọ́ náà. +Mose bá pe Besaleli ati Oholiabu, ati olukuluku àwọn tí OLUWA ti fún ní ìmọ̀ ati òye ati gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ náà láti wá bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. +Lẹ́yìn náà, wọ́n fi igi akasia ṣe àkànpọ̀ igi tí ó dúró lóòró fún àgọ́ náà. +Gígùn àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. +Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn àkànpọ̀ igi náà ní ìkọ́ meji meji láti fi mú wọn pọ̀ mọ́ ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe gbogbo àwọn àkànpọ̀ igi àgọ́ náà. +Wọ́n ṣe ogún àkànpọ̀ igi fún apá gúsù àgọ́ náà, +wọ́n sì ṣe ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka tí wọ́n fi sí abẹ́ ogún àkànpọ̀ igi náà, ìtẹ́lẹ̀ meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan fún àwọn ìkọ́ rẹ̀ mejeeji. +Wọ́n ṣe ogún àkànpọ̀ igi fún ẹ̀gbẹ́ àríwá àgọ́ mímọ́ náà, +pẹlu ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka; ìtẹ́lẹ̀ meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan. +Wọ́n ṣe àkànpọ̀ igi mẹfa fún ẹ̀yìn àgọ́ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn. +Wọ́n sì ṣe àkànpọ̀ igi meji fún igun àgọ́ náà tí ó wà ní apá ẹ̀yìn. +Àwọn àkànpọ̀ igi náà wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìsàlẹ̀, ṣugbọn wọ́n so wọ́n pọ̀ ní òkè ní ibi òrùka kinni, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn àkànpọ̀ igi kinni ati ekeji fún igun mejeeji àgọ́ náà. +Àwọn òṣìṣẹ́ náà gba gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá láti fi ṣe iṣẹ́ àgọ́ mímọ́ náà lọ́wọ́ Mose. Àwọn eniyan ṣá tún ń mú ọrẹ àtinúwá yìí tọ Mose lọ ní àràárọ̀. +Àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní igun kinni-keji jẹ́ mẹjọ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ fadaka mẹrindinlogun, ìtẹ́lẹ̀ meji meji wà lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan. +Wọ́n fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá ìdábùú mẹẹdogun, marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ gúsù, +marun-un fún àwọn ti ẹ̀gbẹ́ àríwá, marun-un fún àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn, lápá ìwọ̀ oòrùn àgọ́ náà. +Wọ́n fi ọ̀pá ìdábùú kan la àwọn àkànpọ̀ igi náà láàrin, ọ̀pá náà kan igun kinni-keji àgọ́ náà. +Wọ́n yọ́ wúrà bo gbogbo àkànpọ̀ igi náà, wọ́n fi wúrà ṣe ìkọ́ fún àwọn àkànpọ̀ igi náà, wọ́n sì yọ́ wúrà bo àwọn ọ̀pá ìdábùú náà pẹlu. +Aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n fi ṣe aṣọ àgọ́ náà, wọ́n sì ya àwòrán Kerubu sí i lára. +Wọ́n fi igi akasia ṣe òpó mẹrin, wọ́n sì yọ́ wúrà bò ó. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn pẹlu, wọ́n sì fi fadaka ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹrin fún àwọn òpó náà. +Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa, ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ọnà aláràbarà sí i lára. +Òpó marun-un ni wọ́n ṣe fún àwọn aṣọ títa náà, wọ́n sì ṣe ìkọ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n yọ́ wúrà bo àwọn òpó náà, ati àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi gbé àwọn aṣọ títa náà kọ́, ṣugbọn idẹ ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn maraarun. +Wọ́n mú ọrẹ wá tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ náà tọ Mose lọ; +wọ́n sọ fún un pé, “Ohun tí àwọn eniyan náà mú wá ti pọ̀ ju ohun tí a nílò láti fi ṣe iṣẹ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wa.” +Mose bá pàṣẹ, wọ́n sì kéde yí gbogbo àgọ́ ká, pé kí ẹnikẹ́ni, kì báà ṣe ọkunrin, tabi obinrin, má wulẹ̀ ṣòpò láti mú ọrẹ wá fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà mọ́. Wọ́n sì dá àwọn eniyan náà lẹ́kun pé kí wọ́n má mú ọrẹ wá mọ́; +nítorí pé ohun tí wọ́n ti mú wá ti tó, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù fún ohun tí wọ́n nílò láti fi ṣe iṣẹ́ náà. +Àwọn tí wọ́n mọ iṣẹ́ jù lára àwọn òṣìṣẹ́ náà kọ́ ibi mímọ́ náà pẹlu aṣọ títa mẹ́wàá. Aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ati aṣọ ẹlẹ́pa ati elése àlùkò ati aṣọ pupa fòò ni wọ́n fi ṣe àwọn aṣọ títa náà, wọ́n sì ya àwòrán kerubu sára rẹ̀; wọn fi dárà sí i. +Gígùn aṣọ títa kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlọgbọn, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, gbogbo wọn rí bákan náà. +Àwọn Eniyan Mú Ọpọlọpọ Ẹ̀bùn Wá. +Besaleli fi igi akasia àpótí ẹ̀rí náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀, ó sì ga ní igbọnwọ kan ààbọ̀. +Ó fi igi akasia kan tabili kan; gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. +Ó yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, ó sì fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀. +Ìgbátí tí ó ṣe náà fẹ̀ ní àtẹ́lẹwọ́ kan ati ààbọ̀. +Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin tabili náà lábẹ́ ìgbátí rẹ̀, +àwọn òrùka yìí ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé tabili náà. +Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá tí wọ́n fi máa ń gbé tabili náà, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n. +Wúrà ni ó fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò tí yóo máa wà lórí tabili náà: àwọn àwo pẹrẹsẹ ati àwọn àwo kòtò fún turari, abọ́, ati ife tí wọn yóo máa fi ta nǹkan sílẹ̀ fún ètùtù. +Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá ìgbámú rẹ̀, àṣepọ̀ ni ó ṣe é, pẹlu àwọn fìtílà rẹ̀, ati àwọn kinní kan bí òdòdó tí ó fi dárà sí i lára. +Ẹ̀ka mẹfa ni ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà; mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji. +Ó ṣe àwọn kinní kan bí òdòdó alimọndi mẹta mẹta sórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà. +Ó yọ́ wúrà bò ó ninu ati lóde, ó sì tún fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀. +Ife mẹrin ni ó ṣe sórí ọ̀pá fìtílà náà gan-an, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí òdòdó alimọndi pẹlu ìrudi ati ìtànná rẹ̀. +Ìrudi kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ẹ̀ka meji meji tí ó so mọ́ ara ọ̀pá fìtílà náà lọ́nà mẹtẹẹta. +Àṣepọ̀ ni ó ṣe ọ̀pá fìtílà ati ẹ̀ka ara rẹ̀ ati ìrudi abẹ́ wọn; ojúlówó wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe wọ́n. +Fìtílà meje ni ó ṣe fún ọ̀pá náà, ojúlówó wúrà ni ó fi ṣe ọ̀pá tí a fi ń pa iná ẹnu fìtílà. +Odidi talẹnti wúrà marundinlaadọrin ni ó lò lórí ọ̀pá fìtílà yìí ati àwọn ohun èlò tí wọ́n jẹ mọ́ ti ọ̀pá fìtílà. +Ó fi igi akasia ṣe pẹpẹ turari kan, bákan náà ni gígùn ati fífẹ̀ rẹ̀ rí, wọ́n jẹ́ igbọnwọ kọ̀ọ̀kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ meji. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe é pẹlu ìwo rẹ̀ mẹrẹẹrin. +Ó yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, ati òkè ati ẹ̀gbẹ́ ati abẹ́ rẹ̀, ati ìwo rẹ̀ pẹlu, ó sì fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀. +Ó da òrùka wúrà meji meji, ó jó wọn mọ́ abẹ́ ìgbátí pẹpẹ náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni-keji, òrùka wọnyi ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé pẹpẹ náà. +Ó fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá rẹ̀, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n. +Ó ṣe òróró ìyàsímímọ́ ati turari olóòórùn dídùn bí àwọn tí wọn ń ṣe turari ṣe máa ń ṣe é. +Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà, òrùka meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji. +Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n. +Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ inú àwọn òrùka tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà láti máa fi gbé e. +Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. +Ó sì fi wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ṣe àwọn Kerubu meji, ó jó wọn mọ́ igun kinni keji ìtẹ́ àánú náà, +Kerubu kinni wà ní igun kinni, Kerubu keji sì wà ní igun keji. +Àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú náà; wọ́n kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìtẹ́ àánú. +Kíkan Àpótí Ẹ̀rí. +Ó fi igi akasia ṣe pẹpẹ ẹbọ sísun, bákan náà ni gígùn ati fífẹ̀ pẹpẹ náà rí, wọ́n jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹta. +Ogún ni àwọn òpó aṣọ títa, àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn náà sì jẹ́ ogún. Idẹ ni ó fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn, ṣugbọn fadaka ni ó fi ṣe ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn. +Gígùn apá àríwá àgọ́ náà jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ pẹlu, ogún ni àwọn òpó rẹ̀, àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn sì jẹ́ ogún pẹlu. Idẹ ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn, ṣugbọn fadaka ni wọ́n fi ṣe ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn. +Gígùn aṣọ títa fún apá ìwọ̀ oòrùn jẹ́ aadọta igbọnwọ, òpó rẹ̀ jẹ́ mẹ́wàá, àwọn àtẹ̀bọ̀ rẹ̀ náà jẹ́ mẹ́wàá; fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn. +Aṣọ títa ti iwájú àgọ́ náà, ní apá ìlà oòrùn gùn ní ìwọ̀n aadọta igbọnwọ. +Aṣọ títa fún apá kan ẹnu ọ̀nà jẹ́ igbọnwọ mẹẹdogun, ó ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta. +Bákan náà ni aṣọ títa ẹ̀gbẹ́ kinni keji ẹnu ọ̀nà náà rí, wọ́n gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹẹdogun mẹẹdogun, wọ́n ní òpó mẹta mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta mẹta. +Aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n fi ṣe gbogbo aṣọ títa tí ó wà ninu àgbàlá náà. +Idẹ ni wọ́n fi ṣe gbogbo àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó rẹ̀; ṣugbọn fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn, fadaka ni wọ́n yọ́ bo àwọn ìbòrí wọn, fadaka ni wọ́n sì fi bo gbogbo àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ fún aṣọ títa wọn. +Wọ́n fi abẹ́rẹ́ ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ títa ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró, ati aṣọ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ó gùn ní ogún igbọnwọ, ó sì ga ní igbọnwọ marun-un gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣọ títa ti àgbàlá náà. +Òpó mẹrin ni aṣọ títa tí ẹnu ọ̀nà yìí ní, pẹlu ìtẹ́lẹ̀ idẹ mẹrin. Fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, fadaka ni wọ́n sì fi bo àwọn ìbòrí òpó náà. +Ó ṣe ìwo kọ̀ọ̀kan sí igun mẹrẹẹrin pẹpẹ náà, àṣepọ̀ mọ́ pẹpẹ ni ó ṣe àwọn ìwo náà, ó sì yọ́ idẹ bò wọ́n. +Idẹ ni wọ́n fi ṣe gbogbo àwọn èèkàn àgọ́ náà, ati ti gbogbo àgbàlá rẹ̀. +Ìṣirò ohun tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ ẹ̀rí wíwà OLUWA nìyí: Mose ni ó pàṣẹ pé kí ọmọ Lefi ṣe ìṣirò àwọn ohun tí wọ́n lò lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni, alufaa. +Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun pa láṣẹ fún Mose. +Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, wà pẹlu rẹ̀. Oholiabu yìí mọ iṣẹ́ ọnà gan-an. Bákan náà, ó lè lo aṣọ aláwọ̀ aró ati elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà. +Gbogbo wúrà tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ náà jẹ́ ìwọ̀n talẹnti mọkandinlọgbọn ati ẹẹdẹgbẹrin ìwọ̀n ṣekeli ó lé ọgbọ̀n (730), ìwọ̀n tí wọn ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. +Fadaka tí àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn eniyan náà dájọ jẹ́ ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti, ati ẹẹdẹgbẹsan ìwọ̀n ṣekeli ó lé marundinlọgọrin (1,775), ìwọ̀n tí wọ́n máa ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n dá wúrà ati fadaka ati idẹ yìí jọ. +Olukuluku àwọn tí wọ́n tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n kà dá ìdajì ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan tí òfin wí, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ilé OLUWA ni wọ́n sì fi wọ̀n ọ́n, iye àwọn eniyan tí wọ́n kà jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ati ẹgbẹtadinlogun ó lé aadọjọ (603,550). +Ọgọrun-un talẹnti fadaka yìí ni wọ́n fi ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó ilé OLUWA ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn aṣọ títa. Ọgọrun-un talẹnti ni wọ́n lò láti ṣe ọgọrun-un ìtẹ́lẹ̀, talẹnti kọ̀ọ̀kan fún ìtẹ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan. +Ninu ẹẹdẹgbẹsan ó lé marundinlọgọrin (1,775) ìwọ̀n ṣekeli fadaka ni ó ti ṣe àwọn ìkọ́ fún àwọn òpó náà, ara rẹ̀ ni ó yọ́ lé àwọn ìbòrí wọn, tí ó sì tún fi ṣe àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ fún aṣọ títa wọn. +Àwọn idẹ tí wọ́n dájọ jẹ́ aadọrin ìwọ̀n talẹnti ati ẹgbaa ó lé irinwo (2,400) ìwọ̀n ṣekeli. +Ó fi idẹ ṣe gbogbo àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ náà: àwọn bíi ìkòkò, ọ̀kọ̀, agbada, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń mú ẹran ati àwo ìfọnná; idẹ ni ó fi ṣe gbogbo wọn. +Idẹ yìí ni ó lò láti ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn ìlẹ̀kùn àgọ́ àjọ, ati pẹpẹ onídẹ, ati àwọn idẹ inú rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò ibi pẹpẹ náà. +Lára rẹ̀ ni wọ́n ti ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó àgọ́ náà yípo ati àwọn èèkàn àgọ́ ati àwọn èèkàn àgbàlá inú rẹ̀. +Ó fi idẹ ṣe ayanran ààrò kan fún pẹpẹ náà, ó ṣe é mọ́ abẹ́ ìgbátí rẹ̀, ayanran náà sì bò ó dé agbede meji sí ìsàlẹ̀. +Ó da òrùka mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan ayanran idẹ náà, àwọn òrùka wọnyi ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé pẹpẹ náà. +Ó fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì yọ́ idẹ bò wọ́n. +Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà láti máa fi gbé e; pákó ni ó fi ṣe àwọn ọ̀pá náà, wọ́n sì ní ihò ninu. +Ó mu dígí onídẹ, tí àwọn obinrin tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ ń lò, ó fi ṣe agbada idẹ kan, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. +Ó ṣe àgbàlá kan, aṣọ funfun, onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ni ó fi ṣe aṣọ títa ìhà gúsù àgbàlá náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ. +Ṣíṣe Pẹpẹ fún Ẹbọ Sísun. +Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa, rán ẹ̀wù aláràbarà tí àwọn alufaa yóo máa wọ̀ ninu ibi mímọ́ náà fún Aaroni gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. +Wọ́n to òkúta olówó iyebíye sí i lára ní ẹsẹ̀ mẹrin, wọ́n to òkúta sadiu ati topasi ati kabọnku sí ẹsẹ̀ kinni, +wọ́n to emeradi ati safire ati dayamọndi sí ẹsẹ̀ keji, +wọ́n to jasiniti, agate ati ametisti sí ẹsẹ̀ kẹta; +wọ́n to bẹrili ati onikisi ati Jasperi sí ẹsẹ̀ kẹrin, wọ́n sì fi ìtẹ́lẹ̀ wúrà jó wọn mọ́ ìgbàyà náà. +Oríṣìí òkúta mejila ni ó wà níbẹ̀; orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dúró fún orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, wọ́n dàbí èdìdì, wọn sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila sí wọn lára, òkúta kan fún ẹ̀yà kan. +Wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe ẹ̀wọ̀n tí a lọ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí okùn fún ìgbàyà náà. +Wọ́n ṣe ojú ìdè wúrà meji, ati òrùka wúrà meji, wọ́n fi òrùka wúrà mejeeji sí etí kinni keji ìgbàyà náà. +Wọ́n ti àwọn ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji náà bọ àwọn òrùka mejeeji tí wọ́n wà ní etí kinni keji ìgbàyà náà. +Wọ́n mú etí kinni keji ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji, wọ́n so wọ́n mọ́ ojú ìdè wúrà ara ìgbàyà náà, wọ́n sì so wọ́n mọ́ èjìká efodu náà. +Lẹ́yìn náà wọ́n da òrùka wúrà meji, wọ́n sì dè wọ́n mọ́ etí kinni keji ìgbàyà náà, lọ́wọ́ inú ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kan ara efodu. +Ó fi wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ rán efodu. +Wọ́n sì da òrùka wúrà meji mìíràn, wọ́n dè wọ́n mọ́ ìsàlẹ̀ èjìká efodu náà níwájú, lókè ibi tí ó ti so pọ̀ mọ́ àmùrè rẹ̀. +Òrùka aṣọ ìgbàyà yìí ni wọ́n fi dè é mọ́ òrùka ara efodu pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan, kí ó lè sùn lé àmùrè efodu náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. +Ó fi aṣọ aláwọ̀ aró rán ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ sí efodu náà, +wọ́n yọ ọrùn sí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà bí ọrùn ẹ̀wù gan-an, wọ́n sì fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ gbá a yípo kí ó má baà ya. +Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe àwòrán èso Pomegiranate sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà nísàlẹ̀. +Wọ́n sì fi agogo ojúlówó wúrà kéékèèké la àwọn àwòrán èso Pomegiranate náà láàrin. +Agogo wúrà kan, àwòrán èso Pomegiranate kan, agogo wúrà kan, àwòrán èso Pomegiranate kan, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tò wọ́n yípo etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà, fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. +Wọ́n fi aṣọ funfun dáradára dá ẹ̀wù meji fún Aaroni ati fún àwọn ọmọ rẹ̀, +wọ́n fi ṣe adé, ati fìlà ati ṣòkòtò. +Wọ́n fi aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ti aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò ati aṣọ pupa tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ṣe àmùrè gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. +Ó fi òòlù lu wúrà, ó sì gé e tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ bí okùn, wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ aláwọ̀ aró ati ti elése àlùkò ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. +Wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe ìgbátí adé mímọ́ náà, wọ́n sì kọ àkọlé kan sí ara rẹ̀ bí wọ́n ti ń kọ ọ́ sí ara òrùka èdìdì, pé, “Mímọ́ fún OLUWA.” +Wọ́n so aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan mọ́ ọn, láti máa fi so ó mọ́ etí adé náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. +Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ àjọ náà ṣe parí, àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. +Wọ́n sì gbé àgọ́ àjọ náà tọ Mose wá, àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀, àwọn ìkọ́ rẹ̀, àwọn àkànpọ̀ igi inú rẹ̀, àwọn igi ìdábùú inú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn; +ìbòrí tí wọ́n fi awọ ewúrẹ́ ati awọ àgbò ṣe tí wọ́n kùn láwọ̀ pupa, ati aṣọ ìbòjú inú àgọ́ náà. +Bẹ́ẹ̀ náà ni àpótí ẹ̀rí pẹlu àwọn òpó rẹ̀ ati ìtẹ́ àánú náà; +ati tabili náà, pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ ati burẹdi ìfihàn. +Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe, ati àwọn fìtílà orí rẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati òróró ìtànná rẹ̀. +Bẹ́ẹ̀ sì ni pẹpẹ wúrà náà, ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn, ati aṣọ títa fún ìlẹ̀kùn àgọ́ mímọ́ náà; +ati pẹpẹ idẹ ati ààrò idẹ rẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati gbogbo ohun èlò rẹ̀, agbada idẹ ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. +Wọ́n ṣe aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ meji fún èjìká efodu náà, wọ́n rán wọn mọ́ ẹ̀gbẹ́ kinni keji rẹ̀ láti máa fi so wọ́n mọ́ ara wọn. +Bẹ́ẹ̀ náà ni aṣọ títa ti àgbàlá náà, àwọn òpó rẹ̀ ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn, ati aṣọ fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, okùn rẹ̀ ati àwọn èèkàn rẹ̀, ati gbogbo ohun èlò fún ìsìn ninu àgọ́ mímọ́ náà, ati fún àgọ́ àjọ náà. +Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀wù tí a ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà sí fún iṣẹ́ ìsìn àwọn alufaa ninu ibi mímọ́, ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa ati ẹ̀wù fún àwọn ọmọ rẹ̀ náà, tí wọn yóo fi máa ṣe iṣẹ́ wọn bí alufaa. +Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, ni àwọn eniyan Israẹli ṣe gbogbo iṣẹ́ náà. +Mose wo gbogbo iṣẹ́ náà, ó rí i pé wọ́n ṣe é gẹ́gẹ́ b�� OLUWA ti pa á láṣẹ, Mose sì súre fún wọn. +Wọ́n fi irú aṣọ kan náà ṣe àmùrè dáradára kan. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe é mọ́ efodu yìí láti máa fi so ó gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. +Wọ́n tọ́jú àwọn òkúta onikisi, wọ́n jó wọn mọ́ ojú ìtẹ́lẹ̀ wúrà, wọ́n kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli sí ara wọn, bí wọ́n ti máa ń kọ orúkọ sí ara òrùka èdìdì. +Ó tò wọ́n sí ara èjìká efodu náà gẹ́gẹ́ bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. +Irú aṣọ tí wọ́n fi ṣe efodu náà ni wọ́n fi ṣe ìgbàyà rẹ̀, wọ́n fi wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe iṣẹ́ ọnà sí i lára. +Bákan náà ni òòró ati ìbú aṣọ ìgbàyà náà, ìṣẹ́po aṣọ meji ni wọ́n sì rán pọ̀. Ìká kan ni òòró rẹ̀, ìká kan náà sì ni ìbú rẹ̀. +Dídá Ẹ̀wù Àwọn Alufaa. +Mose dáhùn pé, “Wọn kò ní gbà mí gbọ́, wọn kò tilẹ̀ ní fetí sí ọ̀rọ̀ mi, wọn yóo wí pé, OLUWA kò farahàn mí.” +Ṣugbọn Mose wí fún OLUWA pé, “OLUWA mi, n kò lè sọ̀rọ̀ dáradára kí o tó bá mi sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni lẹ́yìn tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ tán, nítorí pé akólòlò ni mí.” +OLUWA dá a lóhùn pé, “Ta ló dá ẹnu eniyan? Ta ni í mú kí eniyan ya odi, tabi kí ó ya adití, tabi kí ó ríran, tabi kí ó ya afọ́jú? Ṣebí èmi OLUWA ni. +Nítorí náà, lọ, n óo sì wà pẹlu rẹ, n óo sì máa kọ́ ọ ní ohun tí o óo sọ.” +Ṣugbọn Mose tún ní, “OLUWA mi, mo bẹ̀ ọ́, rán ẹlòmíràn.” +Inú bí OLUWA sí Mose, ó ní, “Ṣebí Aaroni, ọmọ Lefi, arakunrin rẹ wà níbẹ̀? Mo mọ̀ pé òun lè sọ̀rọ̀ dáradára; ó ń bọ̀ wá pàdé rẹ, nígbà tí ó bá rí ọ, inú rẹ̀ yóo dùn gidigidi. +O óo máa bá a sọ̀rọ̀, o óo sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu. N óo gbàkóso ẹnu rẹ ati ẹnu rẹ̀; n óo sì kọ yín ní ohun tí ẹ óo ṣe. +Òun ni yóo máa bá ọ bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀, yóo jẹ́ ẹnu fún ọ, o óo sì dàbí Ọlọrun fún un. +Mú ọ̀pá yìí lọ́wọ́, òun ni o óo máa fi ṣe iṣẹ́ ìyanu.” +Mose pada lọ sí ọ̀dọ̀ Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan mi ní Ijipti, kí n lọ wò ó bóyá wọ́n wà láàyè.” Jẹtiro dá Mose lóhùn pé, “Máa lọ ní alaafia.” +OLUWA sọ fún Mose ní Midiani pé, “Pada lọ sí Ijipti, nítorí pé gbogbo àwọn tí wọn ń lépa ẹ̀mí rẹ ti kú tán.” +OLUWA bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló wà ní ọwọ́ rẹ yìí?” Ó dáhùn pé, “Ọ̀pá ni.” +Mose bá gbé iyawo rẹ̀ ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tòun ti ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ rẹ̀. +OLUWA sọ fún Mose pé, “Nígbà tí o bá pada dé Ijipti, o gbọdọ̀ ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí mo fún ọ lágbára láti ṣe níwájú Farao, ṣugbọn n ó mú kí ọkàn rẹ̀ le, kò sì ní jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli lọ. +O óo wí fún un pé, Èmi, OLUWA wí pé, ‘Israẹli ni àkọ́bí mi ọkunrin. +Nítorí náà, jẹ́ kí ọmọ mi lọ, kí ó lè sìn mí. Bí o bá kọ̀, tí o kò jẹ́ kí ó lọ, pípa ni n óo pa àkọ́bí rẹ ọkunrin.’ ” +Nígbà tí wọ́n dé ilé èrò kan ní ojú ọ̀nà Ijipti, OLUWA pàdé Mose, ó sì fẹ́ pa á. +Sipora bá mú akọ òkúta pẹlẹbẹ tí ó mú, ó fi kọ ilà abẹ́ fún ọmọ rẹ̀, ó sì fi awọ tí ó gé kúrò kan ẹsẹ̀ Mose, ó wí fún Mose pé, “Ọkọ tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gba kí á ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ni ọ́.” +OLUWA bá fi Mose sílẹ̀, kò pa á mọ́. Nítorí àṣà ilà abẹ́ kíkọ náà ni Sipora ṣe wí pé, ọkọ tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gba kí á ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ni Mose. +OLUWA wí fún Aaroni pé, “Jáde lọ sinu aṣálẹ̀, kí o lọ pàdé Mose.” Ó jáde lọ, ó pàdé rẹ̀ ní òkè Ọlọrun, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. +Mose sọ gbogbo iṣẹ́ tí OLUWA rán an fún un, ati gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí OLUWA pa láṣẹ pé kí ó ṣe. +Mose ati Aaroni bá lọ sí Ijipti, wọ́n kó gbogbo àgbààgbà àwọn eniyan Israẹli jọ. +OLUWA ní, “Sọ ọ́ sílẹ̀.” Mose bá sọ ọ́ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò, Mose bá sá sẹ́yìn. +Aaroni sọ gbogbo ohun tí OLUWA sọ fún Mose fún wọn, ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu náà lójú gbogbo àwọn àgbààgbà náà. +Àwọn eniyan náà gba ọ̀rọ̀ wọn gbọ́; nígbà tí wọ́n gbọ́ pé OLUWA wá bẹ àwọn eniyan Israẹli wò, ati pé ó ti rí ìpọ́njú wọn, wọ́n tẹríba, wọ́n sì sin OLUWA. +Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ, kí o mú un ní ìrù.” Mose nawọ́ mú un, ejò náà sì pada di ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀. +OLUWA wí pé, “Èyí yóo mú kí wọ́n gbàgbọ́ pé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu ni ó farahàn ọ́.” +OLUWA tún wí fún un pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá. Nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ dẹ́tẹ̀, ó sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. +Ọlọrun tún ní, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá pada.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá rẹ̀ pada; nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀. +Ọlọrun ní, “Bí wọn kò bá fẹ́ gbà ọ́ gbọ́, tabi bí wọn kò bá náání àmì ti àkọ́kọ́, ó ṣeéṣe kí wọ́n gba àmì keji yìí gbọ́. +Bí wọn kò bá gba àwọn àmì mejeeji wọnyi gbọ́, tí wọ́n sì kọ̀, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, lọ bu omi díẹ̀ ninu odò Naili kí o sì dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀; omi náà yóo di ẹ̀jẹ̀ bí o bá ti dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀.” +Ọlọrun Fún Mose ní Agbára Ìyanu. +OLUWA sọ fún Mose pé, +Ta òróró sí ara pẹpẹ ẹbọ sísun pẹlu, ati sí ara gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, kí o ya pẹpẹ náà sí mímọ́, pẹpẹ náà yóo sì di ohun mímọ́ jùlọ. +Ta òróró sí ara agbada náà pẹlu ati gbogbo ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, kí o sì yà á sí mímọ́. +“Lẹ́yìn náà, mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n. +Kó àwọn ẹ̀wù mímọ́ náà wọ Aaroni, ta òróró sí i lórí, kí o sì yà á sí mímọ́ kí ó lè máa ṣe alufaa mi. +Kó àwọn ọmọ rẹ̀ wá pẹlu, kí o sì wọ̀ wọ́n ní ẹ̀wù. +Ta òróró sí wọn lórí, gẹ́gẹ́ bí o ti ta á sí baba wọn lórí, kí àwọn náà lè máa ṣe alufaa mi. Òróró tí o bá ta sí wọn lórí ni yóo sọ àwọn ati gbogbo ìran wọn di alufaa títí lae.” +Mose ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un patapata. +Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni ọdún keji ni wọ́n pa àgọ́ náà. +Mose pa àgọ́ mímọ́ náà, ó to àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, ó gbé àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀ lé wọn, ó fi àwọn igi ìdábùú àgọ́ náà dábùú àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀; lẹ́yìn náà, ó gbé àwọn òpó rẹ̀ nàró. +Lẹ́yìn náà, ó ta aṣọ àgọ́ náà bò ó, ó sì fi ìbòrí rẹ̀ bò ó gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. +“Kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ọjọ́ kinni oṣù kinni. +Ó kó àwọn tabili òkúta mejeeji sinu àpótí ẹ̀rí náà, ó ti àwọn ọ̀pá àpótí náà bọ inú àwọn òrùka rẹ̀, ó sì fi ìdérí rẹ̀ dé e lórí. +Ó gbé àpótí ẹ̀rí náà sinu àgọ́ náà, ó sì ta aṣọ ìbòjú rẹ̀ dí i gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. +Ó gbé tabili náà sí inú àgọ́, ní apá ìhà àríwá àgọ́ mímọ́, níwájú aṣọ ìbòjú, +ó sì to àwọn burẹdi náà létòlétò sórí rẹ̀ níwájú OLUWA, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. +Ó gbé ọ̀pá fìtílà náà sinu àgọ́ àjọ níwájú tabili ní apá ìhà gúsù àgọ́ náà. +Ó to àwọn fìtílà rẹ̀ sórí rẹ̀ níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. +Ó gbé pẹpẹ wúrà náà kalẹ̀ ninu àgọ́ àjọ níwájú aṣọ ìbòjú náà, +ó sì sun turari olóòórùn dídùn lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. +Ó ta àwọn aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà sí ààyè wọn. +Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun kalẹ̀ níbi ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. +Kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí tí òfin mẹ́wàá wà ninu rẹ̀ sinu àgọ́ náà, kí o sì ta aṣọ ìbòjú dí i. +Ó gbé agbada omi náà kalẹ̀ ní agbede meji àgọ́ àjọ ati pẹpẹ ẹbọ sísun, ó sì pọn omi sinu rẹ̀. +Omi yìí ni Mose, ati Aaroni ati àwọn ọmọ Aaroni fi ń fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn, +nígbà tí wọ́n bá ń wọ inú àgọ́ àjọ lọ, ati ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ súnmọ́ ìdí pẹpẹ, wọn á fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ. +Ó ṣe àgbàlá kan yí àgọ́ ati pẹpẹ náà ká, ó ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe parí gbogbo iṣẹ́ náà. +Nígbà náà ni ìkùukùu bo àgọ́ àjọ náà, ògo OLUWA sì kún inú rẹ̀. +Mose kò sì lè wọ inú rẹ̀ nítorí ìkùukùu tí ó wà lórí rẹ̀, ati pé ògo OLUWA kún inú rẹ̀. +Ninu gbogbo ìrìn àjò wọn, nígbà tí ìkùukùu yìí bá gbéra kúrò lórí àgọ́ náà, àwọn ọmọ Israẹli á gbéra, wọ́n á sì tẹ̀síwájú. +Ṣugbọn bí ìkùukùu yìí kò bá tíì gbéra, àwọn náà kò ní tíì tẹ̀síwájú títí tí yóo fi gbéra. +Nítorí pé ninu gbogbo ìrìn àjò wọn, ìkùukùu OLUWA wà lórí àgọ́ náà lọ́sàn-án, iná sì máa ń jó ninu rẹ̀ lóru ní ìṣojú gbogbo àwọn eniyan Israẹli. +Lẹ́yìn náà, gbé tabili náà wọ inú rẹ̀, pẹlu àwọn nǹkan tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, kí o sì tò wọ́n sí ààyè wọn. Lẹ́yìn náà, gbé ọ̀pá fìtílà náà wọ inú rẹ̀, kí o sì to àwọn fìtílà orí rẹ̀ sí ààyè wọn. +Lẹ́yìn náà, gbé pẹpẹ wúrà turari siwaju àpótí ẹ̀rí náà, kí o sì ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà. +Gbé pẹpẹ ẹbọ sísun kalẹ̀ níwájú ẹnu ọ̀nà àgọ́ mímọ́ ti àgọ́ àjọ náà. +Gbé agbada omi náà sí ààrin, ní agbede meji àgọ́ àjọ ati pẹpẹ náà, kí o sì pọn omi sinu rẹ̀. +Lẹ́yìn náà, ṣe àgbàlá yí i ká, kí o sì ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. +“Lẹ́yìn náà, mú òróró ìyàsímímọ́, kí o ta á sí ara àgọ́ náà, ati sí ara ohun gbogbo tí ó wà ninu rẹ̀, kí o yà á sí mímọ́ pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀, wọn yóo sì di mímọ́. +Kíkọ́ ati Yíya Àgọ́ Ìpàdé OLUWA sí Mímọ́. +Lẹ́yìn náà, Mose ati Aaroni lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sọ fún un pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ pé, ‘Jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, kí wọ́n lè lọ ṣe àjọ̀dún kan fún mi ninu aṣálẹ̀.’ ” +Àwọn tí wọn ń kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ bá jáde tọ̀ wọ́n lọ, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ bí Farao ti wí; ó ní òun kò ní fún yín ní koríko mọ́. +Ó ní kí ẹ lọ máa wá koríko fúnra yín níbikíbi tí ẹ bá ti rí. Ṣugbọn iye bíríkì tí ẹ̀ ń mọ tẹ́lẹ̀ kò gbọdọ̀ dín!” +Wọ́n bá fọ́n káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ijipti láti wá àgékù koríko. +Àwọn tí wọn ń kó wọn ṣiṣẹ́ a máa fi ipá mú wọn pé, lojumọ, wọ́n gbọdọ̀ mọ iye bíríkì tí wọ́n máa ń mọ tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọn kò tíì máa wá koríko fúnra wọn. +Àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao bẹ̀rẹ̀ sí na àwọn tí wọ́n fi ṣe olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Wọn á máa bi wọ́n pé “Kí ló dé tí bíríkì tí ẹ mọ lónìí kò fi tó iye tí ó yẹ kí ẹ mọ?” +Àwọn tí wọ́n fi ṣe olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli bá ké tọ Farao lọ, wọ́n ní, “Kí ló dé tí o fi ń ṣe báyìí sí àwa iranṣẹ rẹ? +Ẹnikẹ́ni kò fún wa ní koríko, sibẹ wọ́n ní dandan, a gbọdọ̀ mọ iye bíríkì tí à ń mọ tẹ́lẹ̀. Wọ́n ń lù wá, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ará Ijipti gan-an ni wọ́n jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.” +Ṣugbọn Farao dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀lẹ ni yín, ẹ kò fẹ́ ṣiṣẹ́ ni ẹ fi ń sọ pé kí n jẹ́ kí ẹ lọ rúbọ sí OLUWA. +Ẹ kúrò níwájú mi nisinsinyii, kí ẹ lọ máa ṣiṣẹ́ yín; kò sí ẹni tí yóo fún yín ní koríko, iye bíríkì tí ẹ̀ ń mọ tẹ́lẹ̀ kò sì gbọdọ̀ dín.” +Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn wà ninu ewu, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé iye bíríkì tí àwọn ń mọ lojumọ kò gbọdọ̀ dín rárá. +Ṣugbọn Farao dá wọn lóhùn pé, “Ta ni OLUWA yìí tí n óo fi fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí n sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ? N kò mọ OLUWA ọ̀hún, ati pé n kò tilẹ̀ lè gbà rárá pé kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.” +Bí wọ́n ti ń ti ọ̀dọ̀ Farao bọ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni tí wọ́n dúró dè wọ́n, wọ́n sì sọ fún wọn pé, +“Ọlọrun ni yóo dájọ́ fún yín, ẹ̀yin tí ẹ sọ wá di ẹni ìríra níwájú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ẹ sì ti yọ idà lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n fi pa wá.” +Mose bá tún yipada sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, kí ló dé tí o fi ṣe ibi sí àwọn eniyan wọnyi? Kí ló dé tí o fi rán mi sí wọn? +Nítorí pé, láti ìgbà tí mo ti lọ sí ọ̀dọ̀ Farao láti bá a sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ, ni ó ti ń ṣe àwọn eniyan wọnyi níbi, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì gba àwọn eniyan rẹ sílẹ̀ rárá!” +Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọlọrun àwọn Heberu ni ó farahàn wá; jọ̀wọ́, fún wa ní ààyè láti lọ sí aṣálẹ̀ ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta, kí á lè lọ rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ó má baà fi àjàkálẹ̀ àrùn tabi ogun bá wa jà.” +Ṣugbọn ọba Ijipti dá wọn lóhùn pé, “Ìwọ Mose ati ìwọ Aaroni, kí ló dé tí ẹ fi kó àwọn eniyan wọnyi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ kó wọn pada kíákíá.” +Farao fi kún un pé, “Ṣé ẹ̀yin náà rí i pé àwọn eniyan yìí pọ̀ pupọ ju àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ilẹ̀ yìí lọ, ẹ sì tún kó wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn?” +Ní ọjọ́ náà gan-an ni Farao pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọ̀gá tí wọn ń kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ pé, +“Ẹ kò gbọdọ̀ fún àwọn eniyan wọnyi ní koríko láti fi ṣe bíríkì bí ẹ ti ṣe ń fún wọn tẹ́lẹ̀ mọ; ẹ jẹ́ kí wọn máa lọ kó koríko fúnra w���n. +Iye bíríkì tí wọn ń ṣe tẹ́lẹ̀ kò sì gbọdọ̀ dín; nítorí pé nígbà tí iṣẹ́ kò ká wọn lára ni wọ́n ṣe ń rí ààyè pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ rúbọ sí Ọlọrun wa.’ +Ẹ fi iṣẹ́ kún iṣẹ́ wọn. Nígbà tí iṣẹ́ bá wọ̀ wọ́n lọ́rùn gan-an, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ ń parọ́ fún wọn, wọn kò ní fetí sí i.” +Mose ati Aaroni níwájú Ọba Ijipti. +Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “O óo rí ohun tí n óo ṣe sí ọba Farao; ó fẹ́, ó kọ̀, yóo jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, fúnra rẹ̀ ni yóo sì fi ipá tì wọ́n jáde.” +OLUWA bá sọ fún Mose pé, +“Wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, ọba ilẹ̀ Ijipti, kí o wí fún un pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.” +Ṣugbọn Mose dá OLUWA lóhùn pé, “Àwọn eniyan Israẹli gan-an kò gbọ́ tèmi, báwo ni Farao yóo ṣe gbọ́, èmi akólòlò lásánlàsàn.” +Ṣugbọn Ọlọrun bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ̀, ó wá pàṣẹ ohun tí wọn yóo sọ fún àwọn eniyan Israẹli ati fún Farao, ọba Ijipti, pé kí ó kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. +Èyí ni àkọsílẹ̀ àwọn olórí olórí ninu ìdílé wọn: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu bí ọmọkunrin mẹrin: Hanoku, Palu, Hesironi ati Karimi; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Reubẹni. +Simeoni bí ọmọkunrin mẹfa: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari ati Ṣaulu, tí obinrin ará Kenaani kan bí fún un; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Simeoni. +Lefi bí ọmọ mẹta: Geriṣoni, Kohati ati Merari; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi. Ọdún mẹtadinlogoje (137) ni Lefi gbé láyé. +Geriṣoni bí ọmọ meji: Libini ati Ṣimei, wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé wọn. +Kohati bí ọmọ mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli. Ọdún mẹtalelaadoje (133) ni Kohati gbé láyé. +Merari bí ọmọkunrin meji: Mahili ati Muṣi. Àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi nìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí arọmọdọmọ wọn. +Ọlọrun tún sọ fún Mose pé, “Èmi ni OLUWA. +Amramu fẹ́ Jokebedi, arabinrin baba rẹ̀. Jokebedi sì bí Aaroni ati Mose fún un. Ọdún mẹtadinlogoje (137) ni Amramu gbé láyé. +Iṣari bí ọmọkunrin mẹta: Kora, Nefegi ati Sikiri. +Usieli bí ọmọkunrin mẹta: Miṣaeli, Elisafani ati Sitiri. +Aaroni fẹ́ Eliṣeba ọmọbinrin Aminadabu tíí ṣe arabinrin Naṣoni. Àwọn ọmọ tí ó bí fún un nìwọ̀nyí: Nadabu, Abihu, Eleasari, ati Itamari. +Kora bí ọmọkunrin mẹta: Asiri, Elikana ati Abiasafu; àwọn ni ìdílé Kora. +Eleasari ọmọ Aaroni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin Putieli; ó sì bí Finehasi fún un; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi. +Aaroni ati Mose ni OLUWA pè, tí ó sì wí fún pé kí wọ́n kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. +Àwọn ni wọ́n sọ fún ọba Ijipti pé kí ó dá àwọn eniyan Israẹli sílẹ̀. +Ní ọjọ́ tí OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ Ijipti, +OLUWA sọ fún un pé, “Èmi ni OLUWA, sọ gbogbo ohun tí mo rán ọ fún Farao, ọba Ijipti.” +Mo fara han Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn n kò farahàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLUWA tíí ṣe orúkọ mi gan-an. +Ṣugbọn Mose dáhùn pé, “OLUWA, akólòlò ni mí; báwo ni ọba Farao yóo ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ mi?” +Mo tún bá wọn dá majẹmu pé n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún wọn, ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò. +Mo gbọ́ ìkérora àwọn ọmọ Israẹli tí àwọn ará Ijipti dì ní ìgbèkùn, mo sì ranti majẹmu mi. +Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èmi ni OLUWA, n óo yọ yín jáde kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín, n óo yọ yín kúrò ninu ìgbèkùn wọn, ipá ni n óo sì fi rà yín pada pẹlu ìdájọ́ ńlá. +N óo mu yín gẹ́gẹ́ bí eniyan mi, n óo jẹ́ Ọlọrun yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó fà yín yọ kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín. +N óo sì ko yín wá sí ilẹ̀ tí mo búra láti fún Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; n óo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní, Èmi ni OLUWA.’ ” +Mose sọ ọ̀rọ̀ wọnyi fún àwọn eniyan Israẹli, ṣugbọn wọn kò fetí sí ohun tí ó ń sọ, nítorí pé ìyà burúkú tí wọn ń jẹ ní oko ẹrú ti jẹ́ kí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì. +Ọlọrun Pe Mose. +OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ọlọrun fún Farao, Aaroni, arakunrin rẹ ni yóo sì jẹ́ wolii rẹ. +Mose ati Aaroni bá lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn. Aaroni ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ọ̀pá náà di ejò. +Farao bá pe gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n, ati àwọn oṣó, ati àwọn pidánpidán tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Ijipti, àwọn náà pa idán, wọ́n ṣe bí Aaroni ti ṣe. +Olukuluku wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá wọn sì di ejò ṣugbọn ọ̀pá Aaroni gbé gbogbo ọ̀pá tiwọn mì. +Sibẹsibẹ ọkàn Farao tún le, kò sì gbọ́ tiwọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀. +OLUWA wí fún Mose pé, “Ọkàn Farao ti le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ. +Tọ Farao lọ ní òwúrọ̀, bí ó bá ti ń jáde lọ sí etídò, kí o dúró dè é ní etí bèbè odò, kí o sì mú ọ̀pá tí ó di ejò lọ́wọ́. +Sọ fún un pé, ‘OLUWA, Ọlọrun àwọn Heberu rán mi sí ọ, pé kí o jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ, kí wọ́n lè sin òun ní aṣálẹ̀, sibẹ o kò gbọ́. +OLUWA wí pé ohun tí o óo fi mọ̀ pé òun ni OLUWA nìyí: n óo fi ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ mi yìí lu odò Naili, omi odò náà yóo sì di ẹ̀jẹ̀. +Gbogbo ẹja inú odò náà yóo kú, odò náà yóo sì máa rùn, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti kò ní lè mu omi inú rẹ̀ mọ́.’ ” +OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni pé kí ó mú ọ̀pá rẹ̀, kí ó sì nà án sí orí gbogbo omi ilẹ̀ Ijipti, ati sórí odò wọn, ati sórí adágún tí wọ́n gbẹ́, ati gbogbo ibi tí omi dárogún sí, kí wọ́n lè di ẹ̀jẹ̀, ẹ̀jẹ̀ yóo sì wà níbi gbogbo jákèjádò ilẹ̀ Ijipti; ati omi tí ó wà ninu agbada tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati tinú agbada tí wọ́n fi òkúta gbẹ́.” +Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ; Aaroni, arakunrin rẹ yóo sì sọ fún Farao pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. +Mose ati Aaroni ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA lójú Farao ati lójú gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Aaroni gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ó sì fi lu omi tí ó wà ninu odò Naili, gbogbo omi tí ó wà ninu odò náà sì di ẹ̀jẹ̀. +Gbogbo ẹja tí ó wà ninu odò náà kú, odò sì bẹ̀rẹ̀ sí rùn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti kò fi lè mu omi rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ sì wà níbi gbogbo jákèjádò ilẹ̀ Ijipti. +Ṣugbọn àwọn pidánpidán ilẹ̀ Ijipti lo ọgbọ́n idán wọn, àwọn náà ṣe bí Mose ati Aaroni ti ṣe, tí ó fi jẹ́ pé ọkàn Farao túbọ̀ yigbì sí i, kò sì gbọ́ ohun tí Mose ati Aaroni wí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀. +Dípò bẹ́ẹ̀, Farao yipada, ó lọ sí ilé, kò ka ọ̀rọ̀ náà sí rara. +Gbogbo àwọn ará Ijipti bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́lẹ̀ káàkiri yíká odò Naili, pé bóyá wọn á jẹ́ rí omi mímu nítorí pé wọn kò lè mu omi odò Naili mọ́. +Ọjọ́ meje kọjá, lẹ́yìn tí OLUWA ti fi ọ̀pá lu odò Naili. +Ṣugbọn n óo mú kí ọkàn Farao le, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ó ti wù kí iṣẹ́ ìyanu tí n óo ṣe ní ilẹ̀ Ijipti pọ̀ tó, kò ní gbọ́ tìrẹ. +Nígbà náà ni n óo nawọ́ ìyà sí Ijipti, n óo sì kó àwọn ọmọ Israẹli, ìjọ eniyan mi, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ ìyanu ati ìdájọ́ ńlá. +Àwọn ará Ijipti yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá nawọ́ ìyà sí Ijipti tí mo sì kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò láàrin wọn.” +Mose ati Aaroni bá ṣe bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn. +Nígbà tí Mose ati Aaroni lọ bá Farao sọ̀rọ̀, Mose jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún; Aaroni sì jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelọgọrin. +OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, +“Bí Farao bá wí pé kí ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan fún òun kí òun lè mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, kí ìwọ Mose sọ fún Aaroni pé kí ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao ọba, kí ọ̀pá náà lè di ejò.” +Ọ̀pá Aaroni. +Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún Mose pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, kí o sì wí fún un pé, ‘OLUWA ní, “Jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ sìn mí. +Ọba dáhùn pé, “Ní ọ̀la.”Mose bá wí pé, “Bí o ti wí gan-an ni yóo rí, kí o lè mọ̀ pé kò sí ẹlòmíràn tí ó dàbí OLUWA Ọlọrun wa. +Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà yóo kúrò lọ́dọ̀ rẹ, ati ninu àwọn ilé rẹ, ati lọ́dọ̀ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ; kìkì odò Naili nìkan ni ọ̀pọ̀lọ́ yóo kù sí.” +Mose ati Aaroni bá jáde kúrò níwájú Farao, Mose gbadura sí OLUWA pé kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà kúrò, gẹ́gẹ́ bí òun ati Farao ti jọ ṣe àdéhùn. +OLUWA ṣe ohun tí Mose fi adura bèèrè, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí wọ́n wà ninu gbogbo ilé, ati ní àgbàlá, ati ní gbogbo oko sì kú. +Wọ́n kó wọn jọ ní òkítì òkítì, gbogbo ìlú sì bẹ̀rẹ̀ sí rùn. +Nígbà tí Farao rí i pé gbogbo ọ̀pọ̀lọ́ náà kú tán, ọkàn rẹ̀ tún le, kò sì ṣe ohun tí Mose ati Aaroni wí mọ́, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀. +OLUWA rán Mose pé, kí ó sọ fún Aaroni pé kí ó na ọ̀pá rẹ̀ jáde, kí ó sì fi lu erùpẹ̀ ilẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ sì di iná orí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. +Wọ́n ṣe bí OLUWA ti wí; Aaroni na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀, ó fi lu erùpẹ̀ ilẹ̀, iná sì bo àwọn eniyan ati àwọn ẹranko; gbogbo erùpẹ̀ ilẹ̀ sì di iná ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. +Àwọn pidánpidán náà gbìyànjú láti mú kí iná jáde pẹlu ọgbọ́n idán wọn, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é. Iná bo gbogbo eniyan ati àwọn ẹranko. +Àwọn pidánpidán náà sọ fún Farao pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni èyí.” Ṣugbọn ọkàn Farao le, kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀. +Ṣugbọn bí o bá kọ̀, tí o kò jẹ́ kí wọ́n lọ, n óo da ọ̀pọ̀lọ́ bo ilẹ̀ rẹ. +OLUWA bá tún sọ fún Mose pé, “Dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, kí o lọ dúró de ọba Farao bí ó bá ti ń jáde lọ sétí odò, wí fún un pé, kí ó gbọ́ ohun tí èmi OLUWA wí, pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ sìn mí. +Wí fún un pé, mo ní, tí kò bá jẹ́ kí wọ́n lọ n óo da eṣinṣin bo òun ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀, àwọn ará ilé rẹ̀ ati ti àwọn ará Ijipti, orí ilẹ̀ tí wọ́n dúró lé yóo sì kún fún ọ̀wọ́ eṣinṣin. +Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, èmi OLUWA yóo ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn eniyan mi ń gbé, kí ọ̀wọ́ eṣinṣin má baà lè débẹ̀, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA ní ayé yìí. +Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi ààlà sí ààrin àwọn eniyan mi ati àwọn eniyan rẹ̀. Ní ọ̀la ni iṣẹ́ ìyanu náà yóo ṣẹ.” +OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀; ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ inú ilé Farao ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Ijipti. Eṣinṣin sì ba ilẹ̀ náà jẹ́. +Farao bá pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Ẹ lọ rúbọ sí Ọlọrun yín, ṣugbọn ní ilẹ̀ yìí ni kí ẹ ti rú u.” +Mose dá a lóhùn pé, “Kò ní tọ̀nà bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀; nítorí pé àwọn nǹkan mìíràn lè wà ninu ohun tí a óo fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa tí ó lè jẹ́ ìríra fún àwọn ará Ijipti. Bí a bá fi ohunkohun rúbọ tí ó jẹ́ ìríra lójú àwọn ará Ijipti, ṣé wọn kò ní sọ wá ní òkúta pa? +A níláti lọ sinu aṣálẹ̀ ní ìrìn ọjọ́ mẹta kí á sì rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún wa.” +Farao dáhùn, ó ní, “N óo fún yín láàyè láti lọ rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín ninu aṣalẹ̀, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ lọ jìnnà; ati pé, mo fẹ́ kí ẹ bá mi bẹ Ọlọrun yín.” +Mose bá dáhùn pé, “Wò ó, ń óo jáde kúrò ní iwájú rẹ nisinsinyii, n óo sì lọ gbadura sí OLUWA, kí ọ̀wọ́ eṣinṣin wọnyi lè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀la, kí wọ́n sì kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ ati àwọn eniyan rẹ pẹlu ṣugbọn kí Farao má tún dalẹ̀, kí ó má wí pé àwọn eniyan Israẹli kò gbọdọ̀ lọ rúbọ sí OLUWA.” +Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóo máa gbá yìnìn ninu odò Naili, wọn yóo sì wọ inú ààfin rẹ ati yàrá tí ò ń sùn, wọn yóo gun orí ibùsùn rẹ, wọn yóo sì wọ ilé àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati ti àwọn eniyan rẹ. N óo dà wọ́n sinu ilé ìdáná ati sinu àwo tí wọ́n fi ń tọ́jú oúnjẹ. +Mose bá jáde kúrò níwájú Farao, ó lọ gbadura sí OLUWA, +OLUWA sì ṣe ohun tí Mose bèèrè, ó mú kí ọ̀wọ́ eṣinṣin náà kúrò lọ́dọ̀ Farao ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀. Ó mú kí gbogbo eṣinṣin náà kúrò láìku ẹyọ kan. +Ṣugbọn ọkàn Farao tún le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ. +Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà yóo máa fò mọ́ ìwọ, ati àwọn eniyan rẹ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ.” ’ ” +OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni pé kí ó na ọwọ́ rẹ̀ ati ọ̀pá rẹ̀ sórí àwọn odò ati àwọn adágún tí wọ́n gbẹ́, ati sórí gbogbo ibi tí omi dárogún sí, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ lè jáde sórí ilẹ̀ Ijipti.” +Aaroni bá na ọwọ́ rẹ̀ sí orí gbogbo omi ilẹ̀ Ijipti, ọ̀pọ̀lọ́ bá wọ́ jáde, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti. +Àwọn pidánpidán náà ṣe bẹ́ẹ̀ pẹlu ọgbọ́n idán wọn, wọ́n mú kí ọ̀pọ̀lọ́ bo ilẹ̀ Ijipti. +Nígbà náà ni Farao pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Ẹ bẹ OLUWA kí ó kó ọ̀pọ̀lọ́ kúrò lọ́dọ̀ èmi ati àwọn eniyan mi, n óo sì jẹ́ kí àwọn ará Israẹli lọ rúbọ sí OLUWA.” +Mose dá Farao lóhùn pé, “Sọ ìgbà tí o fẹ́ kí n gbadura fún ìwọ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati àwọn eniyan rẹ, kí Ọlọrun lè run gbogbo àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí wọ́n wà lọ́dọ̀ yín, ati ninu ilé yín; kí ó sì jẹ́ pé kìkì odò Naili nìkan ni ọ̀pọ̀lọ́ yóo kù sí.” +Iná Orí Bo Ilẹ̀. +Ọlọrun tún sọ fún Mose pé kí ó wọlé tọ Farao lọ, kí ó sì sọ fún un pé kí ó gbọ́ ohun tí òun OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu wí, kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ sìn òun. +Mose ati Aaroni bá bu eérú ninu ẹbu, wọ́n dúró níwájú Farao. Mose da eérú náà sókè sí ojú ọ̀run, eérú náà bá di oówo tí ń di egbò lára eniyan ati ẹranko. +Àwọn pidánpidán kò lè dúró níwájú Mose, nítorí pe oówo bo àwọn náà ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti. +Ṣugbọn OLUWA mú kí ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ tiwọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Mose. +OLUWA tún sọ fún Mose pé kí ó dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, kí ó lọ siwaju Farao, kí ó sì sọ fún un pé kí ó gbọ́ ohun tí òun OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu wí, kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ sin òun. +Nítorí pé lọ́tẹ̀ yìí, òun óo da gbogbo àjàkálẹ̀ àrùn òun bo Farao gan-an, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ati àwọn eniyan rẹ̀, kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni tí ó dàbí òun OLUWA ní gbogbo ayé. +Kí ó ranti pé, bí òun OLUWA ti nawọ́ ìyà sí òun ati àwọn eniyan rẹ̀, tí òun sì ti da àjàkálẹ̀ àrùn bò wọ́n; òun ìbá ti pa wọ́n run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, +ṣugbọn ìdí pataki tí òun fi jẹ́ kí wọ́n wà láàyè ni láti fi agbára òun hàn Farao, kí wọ́n lè máa ròyìn orúkọ òun OLUWA káàkiri gbogbo ayé. +Ó ní Farao sì tún ń gbé ara rẹ̀ ga sí àwọn eniyan òun, kò jẹ́ kí wọ́n lọ. +OLUWA ní, “Wò ó, níwòyí ọ̀la, n óo da yìnyín bo ilẹ̀, irú èyí tí kò sí ní ilẹ̀ Ijipti rí, láti ọjọ́ tí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ dó títí di òní yìí. +Nítorí náà, yára ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn ẹran rẹ tí wọ́n wà ninu pápá síbi ìpamọ́, nítorí pé yìnyín yóo rọ̀ sórí eniyan ati ẹranko tí ó bá wà ní pápá, tí wọn kò bá kó wọlé, gbogbo wọn ni yóo sì kú.” +Ati pé, bí ó bá kọ̀, tí kò jẹ́ kí wọ́n lọ, +Nítorí náà gbogbo àwọn tí wọ́n bẹ̀rù ọ̀rọ̀ OLUWA ninu àwọn iranṣẹ Farao pe àwọn ẹrú wọn wálé, wọ́n sì kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wálé pẹlu. +Ṣugbọn àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí fi àwọn ẹrú ati àwọn ohun ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ninu pápá. +OLUWA sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sójú ọ̀run, kí yìnyín lè bọ́ kí ó sì bo ilẹ̀ Ijipti, ati eniyan, ati ẹranko, ati gbogbo ewéko inú ìgbẹ́.” +Mose bá na ọ̀pá rẹ̀ sójú ọ̀run, Ọlọrun sì da ààrá ati yìnyín ati iná bo ilẹ̀, Ọlọrun sì rọ̀jò yìnyín sórí ilẹ̀ Ijipti. +Yìnyín ń bọ́, mànàmáná sì ń kọ yànràn ninu yìnyín náà. Yìnyín náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́; kò tíì sí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti láti ìgbà tí ó ti di orílẹ̀-èdè. +Gbogbo ohun tí ó wà ninu oko ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti ni yìnyín náà dà lulẹ̀, ati eniyan ati ẹranko; o sì wó gbogbo àwọn ohun ọ̀gbìn oko ati gbogbo igi lulẹ̀. +Àfi ilẹ̀ Goṣeni, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé nìkan ni yìnyín yìí kò dé. +Farao bá ranṣẹ pe Mose ati Aaroni, ó sọ fún wọn pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀ nisinsinyii; OLUWA jàre, èmi ati àwọn eniyan mi ni a jẹ̀bi. +Ẹ bẹ OLUWA fún mi nítorí pé yìnyín ati ààrá yìí tó gẹ́ẹ́, n óo jẹ́ kí ẹ lọ, n kò ní da yín dúró mọ́.” +Mose bá dá Farao lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ninu ìlú n óo gbadura sí OLUWA, ààrá kò ní sán mọ́, bẹ́ẹ̀ ni yìnyín kò ní bọ́ mọ́, kí o lè mọ̀ pé, ti OLUWA ni ilẹ̀. +àjàkálẹ̀ àrùn yóo ti ọwọ́ òun OLUWA wá sórí gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí wọ́n wà ní pápá, ati àwọn ẹṣin rẹ̀, ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ati àwọn ràkúnmí rẹ̀, ati àwọn agbo mààlúù rẹ̀, ati àwọn agbo aguntan rẹ̀. +Ṣugbọn mo mọ̀ pé ìwọ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ kò bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun.” +Gbogbo ọ̀gbọ̀ ati ọkà Baali tí ó wà lóko ni ó ti bàjẹ́ patapata, nítorí pé ọkà baali ati ọ̀gbọ̀ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí so ni. +Ṣugbọn ọkà alikama ati ọkà ria kò bàjẹ́, nítorí pé wọn kò tètè hù. +Mose bá kúrò lọ́dọ̀ Farao, ó jáde kúrò ní ìlú; ó gbadura sí OLUWA, ààrá tí ń sán ati yìnyín tí ń bọ́ sì dáwọ́ dúró, òjò náà sì dá lórí ilẹ̀. +Ṣugbọn nígbà tí Farao rí i pé òjò ti dá, ati pé yìnyín ati ààrá ti dáwọ́ dúró, ó tún dẹ́ṣẹ̀, ọkàn rẹ̀ tún le, ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. +Ọkàn rẹ̀ tún le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ láti ẹnu Mose. +Ó ní, Ṣugbọn òun yóo ya àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti, ẹyọ kan ṣoṣo kò ní kú ninu gbogbo àwọn ẹran tíí ṣe ti àwọn ọmọ Israẹli. +OLUWA bá dá àkókò kan, ó ní, “Ní ọ̀la ni èmi OLUWA, yóo ṣe ohun tí mo wí yìí ní ilẹ̀ Ijipti.” +Nígbà tí ó di ọjọ́ keji OLUWA ṣe bí ó ti wí; gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti kú, ṣugbọn ẹyọ kan ṣoṣo kò kú ninu ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. +Farao bá ranṣẹ lọ wo àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì rí i pé ẹyọ kan kò kú ninu wọn. Sibẹsibẹ ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ. +OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé kí wọn bu ẹ̀kúnwọ́ eérú bíi mélòó kan ninu ẹbu, kí Mose dà á sí ojú ọ̀run lójú Farao, +yóo sì di eruku lẹ́búlẹ́bú lórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti, yóo di oówo tí yóo máa di egbò lára eniyan ati ẹranko, ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. +Ikú Àwọn Ẹran Ọ̀sìn. +Ní ọjọ́ karun-un oṣù kẹrin, ní ọgbọ̀n ọdún, èmi, Isikiẹli, ọmọ Busi, wà láàrin àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ Babiloni. A wà lẹ́bàá odò Kebari, mo bá rí i tí ojú ọ̀run ṣí sílẹ̀; mo sì rí ìran Ọlọrun. +Báyìí ni ojú wọn rí: olukuluku wọn ní ojú eniyan níwájú, àwọn mẹrẹẹrin ní ojú kinniun lápá ọ̀tún, wọ́n ní ojú akọ mààlúù lápá òsì, wọ́n sì ní ojú ẹyẹ idì lẹ́yìn. +Wọ́n na ìyẹ́ wọn sókè, ọ̀kọ̀ọ̀kan na ìyẹ́ meji meji kan ìyẹ́ ẹni tí ó kángun sí i, wọ́n sì fi ìyẹ́ meji meji bora. +Olukuluku kọjú sí ìhà mẹrin, ó sì lè lọ tààrà sí ìhà ibi tí ẹ̀mí rẹ̀ bá darí sí láì ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada kí ó tó máa lọ. +Nǹkankan wà láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè náà tí ó dàbí ẹ̀yinná tí ń jó. Ó ń lọ sókè sódò láàrin wọn bí ahọ́n iná. Iná náà mọ́lẹ̀, ó sì ń kọ mànàmànà. +Àwọn ẹ̀dá alààyè náà ń já lọ sókè sódò bí ìgbà tí manamana bá ń kọ. +Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè náà, mo rí àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrin lórí ilẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, àgbá kọ̀ọ̀kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan. +Ìrísí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ati bí a ti ṣe wọ́n nìyí: wọ́n ń dán yànrànyànràn bí òkúta kirisolite. Bákan náà ni àwọn mẹrẹẹrin rí. A ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí ìgbà tí àgbá meji bá wọ inú ara wọn. +Bí wọ́n ti ń lọ, ìhà ibi tí wọn bá fẹ́ ninu ìhà mẹrẹẹrin ni wọ́n lè máa lọ láì ṣẹ̀ṣẹ̀ yíjú pada, kí wọ́n tó máa lọ. +(Àgbá mẹrẹẹrin ní irin tẹẹrẹtẹẹrẹ tí ó so ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn pọ̀). Wọ́n ga, wọ́n ba eniyan lẹ́rù. Àwọn àgbá mẹrẹẹrin ní ojú yíká wọn. +Bí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá ti ń lọ ni àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a máa yí tẹ̀lé wọn, bí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá gbéra nílẹ̀ àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a sì gbéra nílẹ̀ pẹlu. +Lọ́jọ́ karun-un oṣù náà, tíí ṣe ọdún karun-un tí wọ́n ti mú ọba Jehoiakini lọ sí ìgbèkùn, +Ibikíbi tí ẹ̀mí bá fẹ́ lọ ni àwọn ẹ̀dá náà máa ń lọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a sì máa yí lọ pẹlu wọn, nítorí pé ninu àwọn àgbá náà ni ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà. +Bí wọn bá ń lọ àwọn àgbá náà a máa yí lọ pẹlu wọn. Bí wọ́n bá dúró àwọn àgbá náà a dúró. Bí wọn bá gbéra nílẹ̀, àwọn àgbá náà a gbéra nílẹ̀, nítorí pé ninu àwọn àgbá wọnyi ni ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà. +Kinní kan bí awọsanma tí ó ń dán bíi Kristali wà lórí àwọn ẹ̀dá alààyè náà, ó tàn bo gbogbo orí wọn. +Lábẹ́ kinní bí awọsanma yìí ni àwọn ìyẹ́ wọn ti nà jáde, wọ́n kan ara wọn, àwọn ẹ̀dá alààyè náà ní ìyẹ́ meji meji tí wọ́n fi bora. +Bí wọ́n ti ń lọ, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn, ó dàbí ariwo odò ńlá, bí ààrá Olodumare, bí ariwo ìdágìrì ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Bí wọ́n bá dúró, wọn a ká ìyẹ́ wọn wálẹ̀, +nǹkankan a sì máa dún lókè awọsanma tí ó wà lórí wọn. Bí wọn bá ti dúró, wọn a ká ìyẹ́ wọn wálẹ̀. +Mo rí kinní kan lókè awọsanma tí ó wà lórí wọn, ó dàbí ìtẹ́ tí a fi òkúta safire ṣe; mo sì rí kinní kan tí ó dàbí eniyan, ó jókòó lórí nǹkankan bí ìtẹ́ náà. +Mo wò ó láti ibi tí ó dàbí ìbàdí rẹ̀ lọ sókè, ó rí bíi bàbà dídán, ó dàbí iná yíká. Mo wò ó láti ibi ìbàdí lọ sí ìsàlẹ̀, ó dàbí iná. Ìmọ́lẹ̀ sì wà ní gbogbo àyíká rẹ̀. +Ìmọ́lẹ̀ tí ó yí i ká dàbí òṣùmàrè tí ó yọ ninu ìkùukùu lákòókò òjò. Bẹ́ẹ̀ ni àfiwé ìfarahàn ògo OLUWA rí. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo bá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ń sọ̀rọ̀. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea lẹ́bàá odò Kebari; agbára OLUWA sì sọ̀kalẹ̀ sí mi lára. +Ninu ìran náà, mo rí i tí ìjì kan ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá, pẹlu ìkùukùu ńlá tí ìmọ́lẹ̀ ńlá ati iná tí ń kọ mànàmànà yí ìjì náà ká, ààrin iná náà sì dàbí idẹ dídán tí ń kọ mànà. +Láàrin iná yìí, mo rí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan, wọ́n dàbí eniyan. +Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ojú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin. +Ẹsẹ̀ wọn tọ́, àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì dàbí pátákò mààlúù, ó ń kọ mànà bíi idẹ. +Wọ́n ní ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn mẹrẹẹrin, wọ́n ní ojú mẹ́rin ati ìyẹ́ mẹ́rin. +Báyìí ni ojú àwọn mẹrẹẹrin ati ìyẹ́ wọn rí: Ìyẹ́ wọn ń kan ara wọn; bí wọ́n bá ń rìn, olukuluku wọn á máa lọ siwaju tààrà, láìyà sí ibikíbi, bí wọn tí ń lọ. +ÌRAN TÍ ỌLỌRUN KỌ́KỌ́ FIHAN ISIKIẸLI. +Lẹ́yìn náà, mo wo orí àwọn Kerubu, mo rí kinní kan róbótó róbótó, wọ́n dàbí òkúta safire, ìrísí wọn dàbí ìtẹ́. +Àwọn mẹrẹẹrin rí bákan náà, ó sì dàbí ìgbà tí àwọn àgbá náà wọnú ara wọn. +Bí wọn tí ń lọ, ibikíbi tí ó bá wu àwọn Kerubu náà ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin tí wọ́n kọjú sí ni wọ́n lè lọ láì jẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada, nítorí pé ibikíbi tí èyí tí ó wà níwájú bá kọjú sí ni àwọn yòókù máa ń lọ. +Gbogbo ara wọn àtẹ̀yìn wọn, àtọwọ́, àtìyẹ́ ati gbogbo ẹ̀gbẹ́ kẹ̀kẹ́ wọn kún fún ojú. +Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn àgbá náà ní àgbá tí ń sáré yí. +Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní iwájú mẹrin mẹrin. Iwájú kinni jẹ́ iwájú Kerubu, ekeji jẹ́ iwájú eniyan, ẹkẹta jẹ́ iwájú kinniun, ẹkẹrin sì jẹ́ iwájú ẹyẹ idì. +Àwọn Kerubu náà bá gbéra nílẹ̀, àwọn ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí ní etí odò Kebari. +Bí wọn tí ń lọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbá náà ń lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Bí àwọn Kerubu náà bá fẹ́ fò, tí wọ́n bá na ìyẹ́ apá wọn, àwọn àgbá náà kìí kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. +Bí wọn bá dúró, àwọn náà á dúró. Bí wọn bá gbéra nílẹ̀, àwọn náà á gbéra, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà ninu wọn. +Ìtànṣán ògo OLUWA jáde kúrò ní àbáwọlé, ó sì dúró sí orí àwọn Kerubu náà. +Àwọn Kerubu bá na ìyẹ́ apá wọn, wọ́n gbéra nílẹ̀ lójú mi, bí wọ́n ti ń lọ, àwọn àgbá náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn. +Ọlọrun bá sọ fún ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà pé, “Bọ́ sí ààrin àwọn àgbá tí wọn ń yí, tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn Kerubu. Bu ẹ̀yinná tí ó wà láàrin wọn kún ọwọ́ rẹ, kí o sì fọ́n ọn sórí ìlú yìí káàkiri.” Mo bá rí i tí ó wọlé lọ. +Àwọn wọnyi ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọrun Israẹli ní etí odò Kebari. Mo sì mọ̀ pé Kerubu ni wọ́n. +Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní iwájú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin, wọ́n sì ní ọwọ́ bí ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn. +Bí iwájú àwọn tí mo rí lẹ́bàá odò Kebari ti rí gan-an ni iwájú wọn rí. Olukuluku ń rìn lọ siwaju tààrà. +Ìhà gúsù ilé náà ni àwọn Kerubu dúró sí nígbà tí ọkunrin náà wọlé, ìkùukùu sì bo àgbàlá ààrin ilé náà. +Ìfarahàn ògo OLUWA gbéra kúrò lórí àwọn Kerubu, ó lọ dúró sí àbáwọlé. Ìkùukùu kún gbogbo inú ilé náà, ìmọ́lẹ̀ ògo OLUWA sì kún gbogbo inú àgbàlá. +Ariwo ìyẹ́ àwọn Kerubu náà dé àgbàlá òde. Ó dàbí ìgbà tí Ọlọrun Olodumare bá ń sọ̀rọ̀. +Nígbà tí OLUWA pàṣẹ fún ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà pé kí ó mú iná láàrin àwọn àgbá tí ń yí, tí ó wà láàrin àwọn Kerubu, ọkunrin náà wọlé, ó lọ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbá náà. +Ọ̀kan lára àwọn Kerubu náà na ọwọ́ sí inú iná tí ó wà láàrin wọn, ó bù ú sí ọwọ́ ọkunrin aláṣọ funfun náà. Ọkunrin náà gbà á, ó sì jáde. +Ó dàbí ẹni pé àwọn Kerubu náà ní ọwọ́ bíi ti eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn. +Mo wòye, mo sì rí i pé àgbá mẹrin ni ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn Kerubu náà: àgbá kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Kerubu kọ̀ọ̀kan. Àwọn kẹ̀kẹ́ náà ń dán yinrinyinrin bí òkúta Kirisolite. +Ògo OLUWA Kúrò Ninu Tẹmpili Náà. +Ẹ̀mí gbé mi lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn. Àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan wà lẹ́nu ọ̀nà náà, mo rí i pé àwọn meji láàrin wọn jẹ́ ìjòyè: Jaasanaya, ọmọ Aṣuri, ati Pelataya, ọmọ Bẹnaya. +Idà yóo pa yín, ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. +Ìlú yìí kò ní jẹ́ ìkòkò fun yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní jẹ́ ẹran ninu rẹ̀; ní ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín. +Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA; nítorí pé ẹ kò rìn ninu ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣugbọn ẹ ti gba àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká.” +Bí mo tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ni Pelataya, ọmọ Bẹnaya, bá kú. Mo bá dojúbolẹ̀, mo kígbe sókè, mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o fẹ́ pa àwọn ọmọ Israẹli yòókù tán ni?” +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +“Ìwọ ọmọ eniyan, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn arakunrin wọn, tí ẹ jọ wà ní ìgbèkùn, àní gbogbo ilé Israẹli; wọ́n ń sọ pé, ‘Wọ́n ti lọ jìnnà kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, OLUWA sì ti fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.’ +“Nítorí náà wí fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní, bí mo tilẹ̀ kó wọn lọ jìnnà sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ ayé, sibẹsibẹ mo jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ tí wọ́n lọ. +“Nítorí náà, wí fún wọn pé èmi, ‘OLUWA Ọlọrun ní n óo kó wọn jọ láti ààrin àwọn ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo fọ́n wọn ká sí, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli.’ +Nígbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọn óo ṣa gbogbo ohun ẹ̀gbin ati ìríra rẹ̀ kúrò ninu rẹ̀. +Ó ní, mo sọ pé, n óo fún wọn ní ọkàn kan, n óo fi ẹ̀mí titun sí wọn ninu. N óo yọ ọkàn òkúta kúrò láyà wọn, n óo sì fún wọn ní ọkàn ẹran; +OLUWA sọ fún mi, pé, “Ìwọ Ọmọ eniyan, àwọn tí wọn ń gbèrò ibi nìyí; tí wọn ń fún àwọn eniyan ìlú yìí ní ìmọ̀ràn burúkú. +kí wọ́n lè máa rìn ninu ìlànà mi, kí wọ́n sì lè máa pa òfin mi mọ́. Wọn óo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn. +Ṣugbọn n óo fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn tí ọkàn wọn ń fà sí àwọn ohun ẹ̀gbin ati ìríra. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Lẹ́yìn náà, àwọn Kerubu bá gbéra, wọ́n fò, pẹlu àgbá, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn; ìtànṣán ògo OLUWA Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn. +Ògo OLUWA gbéra kúrò láàrin ìlú náà, ó sì dúró sórí òkè tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn ìlú náà. +Ẹ̀mí bá gbé mi sókè ní ojúran, ó gbé mi wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, ìran tí mo rí bá kúrò lójú mi. +Mo sì sọ gbogbo ohun tí OLUWA fihàn mí fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn. +Wọ́n ń wí pé, ‘àkókò ilé kíkọ́ kò tíì tó. Ìlú yìí dàbí ìkòkò, àwa sì dàbí ẹran.’ +Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nípa wọn, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀.” +Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé mi, ó sọ fún mi, pé, “OLUWA ní, Èrò yín nìyí, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, mo mọ ohun tí ẹ̀ ń rò lọ́kàn, +Ẹ ti pa ọpọlọpọ eniyan ní ààrin ìlú yìí; ẹ sì ti da òkú wọn kún gbogbo ìgboro ati òpópónà ìlú. +“Nítorí náà, àwọn òkú yín tí ẹ dà sí ààrin ìlú yìí ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò, ṣugbọn n óo mu yín kúrò láàrin rẹ̀. +Idà ni ẹ̀ ń bẹ̀rù, idà náà ni n óo sì jẹ́ kí ó pa yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀. +N óo ko yín kúrò ninu ìlú yìí, n óo sì ko yín lé àwọn àjèjì lọ́wọ́. N óo sì ṣe ìdájọ́ yín. +(OLUWA Bá Jerusalẹmu Wí). +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +Wí fún wọn pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá àwọn olórí Jerusalẹmu ati àwọn eniyan Israẹli tí ó kù ninu rẹ̀ wí.’ +Sọ fún wọn pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ fún wọn. Bí o ti ṣe ni wọ́n óo ṣe wọ́n, wọn óo lọ sí ìgbèkùn. +Ẹni tí ó jẹ́ olórí láàrin wọn yóo gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká ní alẹ́, yóo sì jáde kúrò nílùú. Yóo dá odi ìlú lu, yóo gba ibẹ̀ jáde. Yóo fi nǹkan bojú kí ó má ba à rí ilẹ̀. +N óo na àwọ̀n mi lé e lórí, yóo sì kó sinu tàkúté tí mo dẹ sílẹ̀. N óo mú un lọ sí Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea. Kò ní fi ojú rí i, bẹ́ẹ̀ sì ni ibẹ̀ ni yóo kú sí. +Gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká ni n óo túká: gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni n óo sì jẹ́ kí ogun máa lé lọ. +“Wọn óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mo tú wọn ká sórí ilẹ̀ ayé. +N óo jẹ́ kí díẹ̀ ninu wọn bọ́ lọ́wọ́ ogun, ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun ìríra wọn láàrin àwọn tí wọn óo lọ máa gbé; wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +“Ìwọ ọmọ eniyan, máa jẹun. Bí o tí ń jẹun lọ́wọ́, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ máa gbọ̀n, kí o sì máa fi ìwárìrì ati ìbẹ̀rù mu omi rẹ. +Kí o wá sọ fún àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà pé, ‘OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé: Pẹlu ìpayà ni wọn óo máa fi jẹun, tí wọn óo sì máa fi mu omi, nítorí pé ilẹ̀ wọn yóo di ahoro nítorí ìwà ipá tí àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń hù. +“Ìwọ ọmọ eniyan, ààrin àwọn olóríkunkun ni o wà: àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò fi gbọ́ràn, nítorí pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. +Àwọn ìlú tí eniyan ń gbé yóo di òkítì àlàpà, gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ” +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +“Ìwọ ọmọ eniyan, kí ló dé tí wọ́n máa ń pòwe ní ilẹ̀ Israẹli pé, ‘Ọjọ́ ń pẹ́ sí i, gbogbo ìran tí àwọn aríran rí sì já sí òfo.’ +Nítorí náà, sọ fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní pa á ní ilẹ̀ Israẹli mọ́.’ Sọ fún wọn pé: Ọjọ́ ń súnmọ́lé tí gbogbo ìran àwọn aríran yóo ṣẹ. +“Nítorí pé ìran irọ́ tabi àfọ̀ṣẹ ẹ̀tàn yóo dópin láàrin àwọn ọmọ Israẹli. +Ṣugbọn èmi OLUWA yóo sọ ohun tí mo bá fẹ́ sọ, yóo sì ṣẹ. Kò ní falẹ̀ mọ́, ṣugbọn níṣojú ẹ̀yin ìdílé ọlọ̀tẹ̀, ni n óo sọ̀rọ̀, tí n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.” +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ìwọ ọmọ eniyan, gbọ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti ń wí pé, Ìran ọjọ́ iwájú ni ò ń rí, o sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ gbọọrọ. +Nítorí náà, wí fún wọn pé: mo ní n kò ní fi ọ̀rọ̀ mi falẹ̀ mọ́, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ yóo ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.” +“Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, di ẹrù rẹ bíi ti ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn, kí o sì jáde ní ìlú lọ́sàn-án gangan níṣojú wọn. Lọ láti ilé rẹ sí ibòmíràn bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Bóyá yóo yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. +Kó ẹrù rẹ jáde lójú wọn ní ọ̀sán gangan kí ìwọ pàápàá jáde lójú wọn ní ìrọ̀lẹ́ bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. +Dá odi ìlú lu níṣojú wọn, kí o sì gba ibẹ̀ jáde. +Gbé ẹrù rẹ lé èjìká níṣojú wọn, kí o sì jáde ní òru. Fi nǹkan bojú rẹ kí o má baà rí ilẹ̀, nítorí pé ìwọ ni mo ti fi ṣe àmì fún ilé Israẹli.” +Mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Mo gbé ẹrù mi jáde lọ́sàn-án gangan bí ẹrù ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, mo fi ọwọ́ ara mi dá odi ìlú lu, mo sì gba ibẹ̀ jáde lóru. Mo gbé ẹrù mi lé èjìká níṣojú wọn. +Ní òwúrọ̀, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, +ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi kò bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé kí ni ò ń ṣe? +Wolii Gẹ́gẹ́ Bí Ẹni Tí Ó sá fógun. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Nítorí pé wọ́n ti ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà wọ́n ń wí fún wọn pé, ‘Alaafia’ nígbà tí kò sí alaafia. Ati pé nígbà tí àwọn eniyan mi ń mọ odi, àwọn wolii wọnyi ń kùn ún ní ọ̀dà funfun. +Wí fún àwọn tí wọn ń kun odi náà ní ọ̀dà pé, òjò ńlá ń bọ̀, yìnyín ńlá yóo bọ́, ìjì líle yóo jà. +Nígbà tí odi náà bá wó, ǹjẹ́ àwọn eniyan kò ní bi yín pé, ‘Ọ̀dà funfun tí ẹ fi ń kun ara rẹ̀ ńkọ́?’ ” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo fi ibinu mú kí ìjì líle jà, n óo fi ìrúnú rọ ọ̀wààrà òjò ńlá, n óo mú kí yìnyín ńláńlá bọ́ kí ó pa á run. +N óo wó ògiri tí ẹ kùn lẹ́fun, n óo wó o lulẹ̀ débi pé ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo hàn síta. Nígbà tí ó bá wó, ẹ óo ṣègbé ninu rẹ̀. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. +“Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára odi náà ati àwọn tí wọn ń kùn ún lẹ́fun. N óo wí fun yín pé, odi kò sí mọ́, àwọn tí wọn ń kùn ún lẹ́fun náà kò sì sí mọ́; +àwọn wolii Israẹli tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerusalẹmu tí wọn ń ríran alaafia nípa rẹ̀, nígbà tí kò sí alaafia. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun wí.” +OLUWA ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, dojú kọ àwọn ọmọbinrin àwọn eniyan rẹ, tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ti ọkàn wọn. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn, kí o wí pé +èmi OLUWA Ọlọrun sọ pé, ‘Ègbé ni fún àwọn obinrin tí wọn ń so ẹ̀gbà òògùn mọ́ gbogbo eniyan lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń ṣe ìbòjú fún gbogbo eniyan, kí ọwọ́ wọn lè ká eniyan. Ṣé ẹ̀ ń dọdẹ ẹ̀mí àwọn eniyan mi ni, kí ẹ lè dá àwọn ẹlòmíràn sí fún èrè ara yín? +Ẹ ti sọ mí di ẹni ìríra lójú àwọn eniyan mi nítorí ẹ̀kún ọwọ́ ọkà baali mélòó kan ati èérún burẹdi. Ẹ̀ ń pa àwọn tí kò yẹ kí ẹ pa, ẹ sì ń dá àwọn tí kò yẹ kí wọ́n wà láàyè sí, nípa irọ́ tí ẹ̀ ń pa fún àwọn eniyan mi, tí wọn ń fetí sí irọ́ yín.’ +“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn wolii Israẹli. Sọ àsọtẹ́lẹ̀, kí o sì wí fún àwọn tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ti ara wọn pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA!’ ” +“Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Mo kórìíra àwọn ẹ̀gbà ọwọ́, òògùn tí ẹ fi ń dọdẹ ẹ̀mí eniyan. N óo já wọn kúrò lápá yín, n óo sì tú àwọn ẹ̀mí tí ẹ dè sílẹ̀ bí ẹyẹ. +N óo ya ìbòjú yín kúrò, n óo gba àwọn eniyan mi lọ́wọ́ yín. Wọn kò ní jẹ́ ohun ọdẹ lọ́wọ́ yín mọ́, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ +“Nítorí pé ẹ̀ ń fi àrékérekè ba àwọn olódodo lọ́kàn jẹ́, nígbà tí n kò fẹ́ bà wọ́n lọ́kàn jẹ́; ẹ sì ń ṣe onígbọ̀wọ́ àwọn eniyan burúkú kí wọn má baà yipada lọ́nà ibi wọn, kí wọn sì rí ìgbàlà. +Nítorí náà, ẹ kò ní ríran èké mọ́, ẹ kò sì ní woṣẹ́ mọ́. N óo gba àwọn eniyan mi lọ́wọ́ yín, nígbà náà, ni ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” +OLUWA Ọlọrun ní, “Ègbé ni fún àwọn òmùgọ̀ wolii tí wọn ń tẹ̀lé ìmọ̀ ara wọn láì jẹ́ pé wọ́n ríran rárá. +Israẹli, àwọn wolii rẹ dàbí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láàrin òkítì àlàpà. +Wọn kò gun ibi tí odi ti lanu lọ, kí wọn tún un mọ yípo agbo ilé Israẹli, kí ó má baà wó lulẹ̀ lọ́jọ́ ìdájọ́ OLUWA. +Wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké, wọ́n ń woṣẹ́ irọ́, wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA wí báyìí.’ Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò rán wọn níṣẹ́ kankan; sibẹ wọ́n ń retí pé kí OLUWA mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ. +Ǹjẹ́ ìran èké kọ́ ni wọ́n ń rí, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́, nígbàkúùgbà tí wọn bá wí pé, ‘OLUWA wí báyìí’, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò sọ̀rọ̀?” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ, ati ìran èké tí ẹ̀ ń rí, mo lòdì si yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun sọ. +N óo jẹ àwọn wolii tí wọn ń ríran èké níyà ati àwọn tí wọn ń woṣẹ́ irọ́. Wọn kò ní bá àwọn eniyan mi péjọ mọ́, tabi kí á kọ orúkọ wọn mọ́ ilé Israẹli, tabi kí wọ́n wọ ilẹ̀ Israẹli mọ́. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun. +Ìran Ibi Nípa Àwọn Ọkunrin Wolii Èké. +Àwọn àgbààgbà Israẹli kan tọ̀ mí wá, wọ́n jókòó siwaju mi. +Àwọn mejeeji yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Irú ìyà kan náà ni n óo fi jẹ wolii alára ati ẹni tí ó lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. +N óo ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹ̀yin ọmọ Israẹli má baà ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi mọ́, tabi kí ẹ máa fi ẹ̀ṣẹ̀ sọ ara yín di aláìmọ́. Ṣugbọn kí ẹ lè jẹ́ eniyan mi, kí n sì jẹ́ Ọlọrun yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Ìwọ ọmọ eniyan, bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣẹ̀ mí, tí wọ́n ṣe aiṣootọ, tí mo bá run gbogbo oúnjẹ wọn, tí mo mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà, tí mo sì run ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀, +bí àwọn ọkunrin mẹta wọnyi: Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà ninu rẹ̀, ẹ̀mí wọn nìkan ni wọn óo lè fi òdodo wọn gbàlà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Bí mo bá jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú já wọ orílẹ̀-èdè náà, kí wọ́n pa wọ́n lọ́mọ jẹ, tí wọ́n sọ ilẹ̀ náà di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò lè gba ibẹ̀ kọjá mọ́, nítorí àwọn ẹranko tí wọ́n wà níbẹ̀, +bí Noa, ati Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà, ilẹ̀ náà yóo sì di ahoro. +Bí mo bá mú kí ogun jà ní ilẹ̀ náà, tí mo sì pa eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀, +bí àwọn ọkunrin mẹta náà bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA ti wà láàyè, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà. +“Tabi bí mo bá rán àjàkálẹ̀ àrùn sí orílẹ̀-èdè náà, tí mo sì fi ibinu bá a jà, débi pé eniyan kú níbẹ̀, tí mo pa ati eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀, +OLUWA bá bá mi sọ̀rọ̀, +bí Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè fi òdodo wọn gbàlà.” +Nítorí OLUWA Ọlọrun ní, “Báwo ni yóo ti wá burú tó nisinsinyii tí mo rán ìjẹníyà burúkú mẹrin wọnyi sí Jerusalẹmu: ogun, ìyàn, ẹranko burúkú ati àjàkálẹ̀ àrùn láti pa eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀. +Sibẹ bí a bá rí àwọn tí wọ́n yè ninu wọn lọkunrin ati lobinrin, tí wọ́n bá wá sọ́dọ̀ rẹ, tí o rí ìwà ati ìṣe wọn, o óo gbà pé mo jàre ní ti ibi tí mo jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu. +Wọn yóo jẹ́ ìtùnú fún ọ nígbà tí o bá rí ìwà ati ìṣe wọn, O óo sì mọ̀ pé bí kò bá nídìí, n kò ní ṣe gbogbo ohun tí mo ṣe sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọkunrin wọnyi kó oriṣa wọn lé ọkàn, wọ́n sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju wọn. Ṣé wọ́n rò pé n óo dá wọn lóhùn tí wọ́n bá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi? +“Nítorí náà, sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tí ó bá kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn tí ó gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju rẹ̀, tí ó wá tọ wolii wá, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ oriṣa rẹ̀. +Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe, kí n lè dá ọkàn àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi nítorí oriṣa wọn pada. +“Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní kí wọn ronupiwada, kí wọn pada lẹ́yìn àwọn oriṣa wọn, kí wọn yíjú kúrò lára àwọn nǹkan ìríra tí wọn ń bọ +“Nítorí pé bí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yin ọmọ Israẹli tabi ninu àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ ní ilẹ̀ Israẹli bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó Kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn, tí ó sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ ka iwájú rẹ̀, tí ó wá tọ wolii lọ láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ ní orúkọ mi, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn. +N óo dójú lé olúwarẹ̀, n óo fi ṣe ẹni àríkọ́gbọ́n ati àmúpòwe. N óo pa á run láàrin àwọn eniyan mi; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. +“Bí wolii kan bá jẹ́ kí á ṣi òun lọ́nà, tí ó sì sọ̀rọ̀, a jẹ́ pé èmi OLUWA ni mo jẹ́ kí wolii náà ṣìnà, N óo na ọwọ́ ìyà sí i, n óo sì pa á run kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi. +Ọlọrun Fi Ìbọ̀rìṣà Gégùn-ún. +OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +“Ìwọ ọmọ eniyan, ọ̀nà wo ni ẹ̀ka igi àjàrà gbà dára ju ẹ̀ka igi yòókù lọ; àní igi àjàrà tí ó wà láàrin àwọn igi inú igbó? +Ǹjẹ́ ẹnìkan a máa fi igi rẹ̀ ṣe ohunkohun? Àbí wọn a máa gé lára rẹ̀ kí wọn fi gbẹ́ èèkàn tí wọ́n fi ń so nǹkan mọ́lẹ̀? +Iná ni wọ́n ń fi í dá, nígbà tí iná bá jó o lórí, tí ó jó o nídìí, tí ó sì sọ ààrin rẹ̀ di èédú, ṣé ó tún ṣe é fi ṣe ohunkohun? +Nígbà tí ó wà ní odidi, kò wúlò fún nǹkankan. Nígbà tí iná ti jó o, tí ó ti di èédú, ṣé eniyan tún lè fi ṣe ohunkohun?” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Bí ẹ̀ka àjàrà tí mo sọ di igi ìdáná láàrin àwọn igi, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. +N óo dójú lé wọn, bí wọn tilẹ̀ yọ jáde ninu iná, sibẹsibẹ iná ni yóo jó wọn. Nígbà tí mo bá dójú lé wọn, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. +N óo sọ ilẹ̀ náà di ahoro nítorí pé wọ́n ti hùwà aiṣootọ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Òwe Nípa Igi Àjàrà. +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: +Mo wá wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí wọ́n ṣe ọnà sí lára, mo wọ̀ ọ́ ní bàtà aláwọ. Mo wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun, mo sì dá ẹ̀wù siliki fún ọ. +Mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà sí ọ lọ́wọ́; mo sì fi ìlẹ̀kẹ̀ sí ọ lọ́rùn. +Mo fi òrùka sí ọ nímú, mo fi yẹtí sí ọ létí, mo sì fi adé tí ó lẹ́wà dé ọ lórí. +Bẹ́ẹ̀ ni mo fi wúrà ati fadaka ṣe ọ̀ṣọ́ sí ọ lára. Aṣọ funfun ati siliki tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ni mo dá fún ọ. Ò ń jẹ burẹdi tí ó dùn, tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tí ó kúnná ṣe, ò ń lá oyin ati òróró; o dàgbà, o sì di arẹwà, o dàbí Ọbabinrin. +Òkìkí ẹwà rẹ wá kàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè; o dára nítorí pé èmi ni mo fún ọ ní ẹwà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Ṣugbọn o gbójú lé ẹwà rẹ; o di alágbèrè ẹ̀sìn nítorí òkìkí rẹ, o sì ń bá gbogbo àwọn eniyan tí wọn ń kọjá ṣe àgbèrè. +O mú ninu àwọn aṣọ rẹ, o fi ṣe ojúbọ aláràbarà, o sì ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn níbẹ̀. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́. +O mú ninu àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati ti fadaka rẹ, tí mo fún ọ, o fi wọ́n ṣe ère ọkunrin, o sì ń bá wọn ṣe àgbèrè. +O mú aṣọ rẹ tí a ṣe ọnà sí lára, o dà á bò wọ́n. O gbé òróró ati turari mi kalẹ̀ níwájú wọn. +Bẹ́ẹ̀ náà ni oúnjẹ tí mo fún ọ. Mo fún ọ ní ìyẹ̀fun tí ó kúnná, ati òróró, ati oyin pé kí o máa jẹ, ṣugbọn o fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Ìwọ ọmọ eniyan, fi nǹkan ìríra tí Jerusalẹmu ń ṣe hàn án, +“O mú àwọn ọmọ rẹ ọkunrin ati àwọn ọmọ rẹ obinrin tí o bí fún mi, o fi wọ́n rú ẹbọ ohun jíjẹ fún àwọn oriṣa. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ kékeré ni o pe ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè ẹ̀sìn rẹ, +tí o fi ọ̀bẹ dú àwọn ọmọ mi, o fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí àwọn oriṣa? +Nígbà tí ò ń ṣe àgbèrè ati gbogbo nǹkan ìríra rẹ, o kò ranti ìgbà èwe rẹ, nígbà tí o wà ní ìhòòhò goloto, tí ò ń ta ẹsẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀!” +OLUWA Ọlọrun ní, “Lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ ibi wọnyi, o gbé! O gbé! +O mọ ilé gíga fún ara rẹ ní gbogbo gbàgede, o tẹ́ ìtẹ́ gíga fún ara rẹ ní ìta gbangba. +O mọ ìtẹ́ gíga ní òpin gbogbo òpópó. O sì ń ba ẹwà rẹ jẹ́ níbẹ̀, ò ń ta ara rẹ fún gbogbo ọkunrin tí wọn ń kọjá, o sì sọ àgbèrè rẹ di pupọ. +O tún ṣe àgbèrè ẹ̀sìn pẹlu àwọn ará Ijipti, àwọn aládùúgbò rẹ, oníṣekúṣe. Ò ń mú kí ìwà àgbèrè rẹ pọ̀ sí i láti mú mi bínú. +“Ọwọ́ mi wá tẹ̀ ọ́, mo mú ọ kúrò ninu ẹ̀tọ́ rẹ. Mo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ fi ìwọ̀ra gba ohun ìní rẹ, àwọn ará Filistini tí ìwà burúkú rẹ ń tì lójú. +“O bá àwọn ará Asiria ṣe àgbèrè ẹ̀sìn pẹlu, nítorí pé o kò ní ìtẹ́lọ́rùn sibẹ, lẹ́yìn gbogbo àgbèrè tí o ṣe pẹlu wọn, o kò ní ìtẹ́lọ́rùn. +O tún ṣe àgbèrè lọpọlọpọ pẹlu àwọn oníṣòwò ará ilẹ̀ Kalidea, sibẹsibẹ, kò tẹ́ ọ lọ́rùn.” +kí o sì sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Jerusalẹmu pé:“Ilẹ̀ Kenaani ni a bí ọ sí; ibẹ̀ ni orísun rẹ. Ará Amori ni baba rẹ ará Hiti sì ni ìyá rẹ. +OLUWA Ọlọrun ní ọkàn rẹ ti kún fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ jù! Ó ń wò ọ́ bí o tí ń ṣe gbogbo nǹkan wọnyi bí alágbèrè tí kò nítìjú! +O mọ ilé oriṣa sí òpin gbogbo òpópó, o sì ń kọ́ ibi ìrúbọ sí gbogbo gbàgede. Sibẹ o kò ṣe bí àwọn alágbèrè, nítorí pé o kò gba owó. +Ìwọ iyawo onípanṣágà tí ò ń kó àwọn ọkunrin ọlọkunrin wọlé dípò ọkọ rẹ. +Ọkunrin níí máa ń fún àwọn aṣẹ́wó ní ẹ̀bùn, ṣugbọn ní tìrẹ, ìwọ ni ò ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn. O fi ń tù wọ́n lójú, kí wọ́n lè máa wá bá ọ ṣe àgbèrè láti ibi gbogbo. +Àgbèrè tìrẹ yàtọ̀ sí ti àwọn aṣẹ́wó yòókù, kò sí ẹni tí ń wá ọ láti bá ọ ṣe àgbèrè; ìwọ ni ò ń fún ọkunrin ní ẹ̀bùn dípò kí wọ́n fún ọ! Èyí ni àgbèrè tìrẹ fi yàtọ̀ sí ti àwọn ẹlòmíràn. +Nítorí náà, ìwọ aṣẹ́wó yìí, gbọ́ ohun tí OLUWA wí. +OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwà ìtìjú rẹ ti hàn sí gbangba, o bọ́ra sí ìhòòhò níta, nígbà tí ò ń bá àwọn olólùfẹ́ rẹ ṣe àgbèrè, tí ò ń bọ àwọn oriṣa rẹ, o sì pa àwọn ọmọ rẹ, o fi wọ́n rúbọ sí àwọn oriṣa. +Wò ó! N óo kó gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ, tí inú rẹ dùn sí jọ, ati àwọn tí o fẹ́ràn ati àwọn tí o kórìíra, ni n óo kó wá láti dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà. N óo tú ọ sí ìhòòhò lójú wọn, kí wọ́n lè rí ìhòòhò rẹ. +N óo ṣe ìdájọ́ fún ọ bí wọn tí ń ṣe ìdájọ́ fún àwọn obinrin tí wọ́n kọ ọkọ sílẹ̀, tabi àwọn tí wọ́n paniyan. N óo fi ìtara ati ibinu gbẹ̀san ìpànìyàn lára rẹ. +N óo fi ọ́ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọ́wọ́, wọn óo wó ilé oriṣa ati ibi ìrúbọ rẹ palẹ̀. Wọn óo tú aṣọ rẹ, wọn óo gba àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò. +Bí wọn ṣe bí ọ nìyí: nígbà tí wọ́n bí ọ, wọn kò dá ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi omi wẹ̀ ọ́. Wọn kò fi iyọ̀ pa ọ́ lára, wọn kò sì fi aṣọ wé ọ. +“Wọn óo kó àwọn ọmọ ogun wá bá ọ, wọn óo sọ ọ́ lókùúta, wọn óo sì fi idà wọn gé ọ sí wẹ́wẹ́. +Wọn óo dáná sun àwọn ilé rẹ, wọn óo sì ṣe ìdájọ́ fún ọ lójú àwọn obinrin pupọ. N kò ní jẹ́ kí o ṣe àgbèrè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní jẹ́ kí o fún àwọn olólùfẹ́ rẹ ní ẹ̀bùn mọ́. +Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára rẹ, n kò sì ní jowú nítorí rẹ mọ́. Ara mi yóo rọlẹ̀, inú kò sì ní bí mi mọ́. +Nítorí pé o kò ranti ìgbà èwe rẹ, ṣugbọn o mú mi bínú nítorí nǹkan wọnyi. Nítorí náà n óo da èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lé ọ lórí. Ṣé o kò tún ti fi ìwà ainitiju kún ìwà ìríra rẹ?” OLUWA Ọlọrun ni ó sọ bẹ́ẹ̀. +OLUWA ní: “Gbogbo eniyan ni yóo máa pa òwe yìí mọ́ ìwọ Jerusalẹmu pé: ‘Òwú ìyá gbọ̀n ni ọmọ óo ran, b�� ìyá bá ti rí ni ọmọ rẹ̀ obinrin yóo rí.’ +Ọmọ bíbí inú ìyá rẹ ni ọ́, tí kò bìkítà fún ọkọ ati àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwà kan náà ni ó wà lọ́wọ́ ìwọ ati àwọn arabinrin rẹ, àwọn náà kò ka ọkọ ati àwọn ọmọ wọn sí. Ará Hiti ni ìyá rẹ, ará Amori sì ni baba rẹ. +“Samaria ni ẹ̀gbọ́n rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé ìhà àríwá. Sodomu ni àbúrò rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé ìhà gúsù. +Títẹ̀lé ìṣe wọn nìkan kò tẹ́ ọ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni ṣíṣe ohun ìríra bíi tiwọn kò tó ọ. Láìpẹ́ ọjọ́, ìwà tìrẹ gan-an yóo burú ju tiwọn lọ. +“Èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, Sodomu arabinrin rẹ ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin kò tíì ṣe tó ohun tí ìwọ ati àwọn ọmọbinrin rẹ ṣe. +Ohun tí Sodomu arabinrin rẹ ṣe tí kò dára ni pé: Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin ní ìgbéraga. Wọ́n ní oúnjẹ lọpọlọpọ, ara sì rọ̀ wọ́n, ṣugbọn wọn kò ran talaka ati aláìní lọ́wọ́. +Ẹnikẹ́ni kò wò ọ́ lójú, kí ó ṣàánú rẹ, kí ó ṣe ọ̀kan kan ninu àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì fún ọ. Ṣugbọn wọ́n gbé ọ sọ sinu pápá, nítorí pé wọ́n kórìíra rẹ ní ọjọ́ tí wọ́n bí ọ. +Wọ́n gbéraga, wọ́n sì ṣe nǹkan ìríra níwájú mi. Nítorí náà, nígbà tí mo rí ohun tí wọn ń ṣe, mo pa wọ́n run. +“Ẹ̀ṣẹ̀ tí Samaria dá kò tó ìdajì èyí tí ìwọ dá, ohun ìríra tí o ṣe sì jù tiwọn lọ. O ti mú kí arabinrin rẹ dàbí olódodo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, nítorí pé nǹkan ìríra tí o ṣe pọ̀ pupọ ju tirẹ̀ lọ. +Ó yẹ kí ojú ti ìwọ pàápàá, nítorí o ti jẹ́ kí ìdájọ́ gbe àwọn arabinrin rẹ, nítorí nǹkan ìríra tí o ṣe ju tiwọn lọ. Ọ̀nà wọn tọ́ ju tìrẹ lọ, nítorí náà, ó yẹ kí ojú tì ọ́, nítorí o ti mú kí àwọn arabinrin rẹ dàbí olódodo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.” +OLUWA sọ níti Jerusalẹmu pé, “N óo dá ire wọn pada: ire Sodomu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin ati ire Samaria ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin. N óo dá ire tìrẹ náà pada pẹlu tiwọn. +Kí ojú lè tì ọ́ fún gbogbo ohun tí o ṣe tí o fi dá wọn lọ́kàn le. +Ní ti àwọn arabinrin rẹ: Sodomu ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin yóo pada sí ibùgbé wọn, Samaria ati àwọn ọmọ rẹ obinrin yóo pada sí ibùgbé wọn, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin náà yóo pada sí ibùgbé yín. +Ṣebí yẹ̀yẹ́ ni ò ń fi Sodomu arabinrin rẹ ṣe ní àkókò tí ò ń gbéraga, +kí ó tó di pé àṣírí ìwà burúkú rẹ wá tú? Nisinsinyii ìwọ náà ti dàbí rẹ̀; o ti di ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọbinrin Edomu ati àwọn tí ó wà ní agbègbè wọn, ati lọ́wọ́ àwọn ọmọbinrin Filistini, ati àwọn tí wọ́n yí ọ ká, tí wọn ń kẹ́gàn rẹ. +O óo jìyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ati àwọn nǹkan ìríra tí o ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +Láìṣe àní, àní, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ṣe sí ọ, bí ìwà rẹ. O kò ka ìbúra mi sí, o sì ti yẹ majẹmu mi. +“Bí mo tí ń rékọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, mo rí ọ tí ò ń ta ẹsẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀. Bí o tí ń yí ninu ẹ̀jẹ̀, mo bá sọ fún ọ pé kí o yè, +Sibẹsibẹ, n óo ranti majẹmu tí mo bá ọ dá ní ìgbà èwe rẹ. N óo sì bá ọ dá majẹmu tí kò ní yẹ̀ títí lae. +O óo wá ranti gbogbo ìwà rẹ, ojú yóo sì tì ọ́ nígbà tí mo bá mú ẹ̀gbọ́n rẹ obinrin ati àbúrò rẹ obinrin, tí mo sì fà wọ́n lé ọ lọ́wọ́ bí ọmọ; ṣugbọn tí kò ní jẹ́ pé torí majẹmu tí mo bá ọ dá ni. +N óo fìdí majẹmu tí mo bá ọ dá múlẹ̀. O óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA. +Kí o lè ranti, kí ìdààmú sì bá ọ, kí ìtìjú má jẹ́ kí o lè lanu sọ̀rọ̀ mọ́; nígbà tí mo bá dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” +kí o sì dàgbà bí irúgbìn oko. Ni o bá dàgbà, o ga, o sì di wundia, ọyàn rẹ yọ, irun rẹ sì hù, sibẹ o wà ní ìhòòhò. +“Ìgbà tí mo tún kọjá lọ́dọ̀ rẹ, tí mo tún wò ọ́, o ti dàgbà o tó gbé. Mo bá da aṣọ mi bò ọ́, mo fi bo ìhòòhò rẹ. Mo ṣe ìlérí fún ọ, mo bá ọ dá majẹmu, o sì di tèmi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. +“Lẹ́yìn náà, mo mú omi, mo wẹ̀ ọ́; mo fọ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ, mo sì fi òróró pa ọ́ lára. +Ìtàn Jerusalẹmu. +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +Nígbà tí wọ́n bá tún un gbìn ǹjẹ́ yóo yè? Ṣé kò ní gbẹ patapata nígbà tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn bá fẹ́ lù ú? Yóo gbẹ níbi tí wọ́n gbìn ín sí.” +Lẹ́yìn náà, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, +“Bi àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi pé, ṣé wọn kò mọ ìtumọ̀ òwe wọnyi ni? Sọ pé ọba Babiloni wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Babiloni. +Ó mú ọ̀kan ninu àwọn ìdílé ọba, ó bá a dá majẹmu, ó sì mú kí ó búra. Ó ti kọ́ kó gbogbo àwọn eniyan pataki pataki ilẹ̀ náà lọ, +kí ilẹ̀ náà lè di ìrẹ̀sílẹ̀, kí wọ́n má sì lè gbérí mọ́, ṣugbọn kí ilẹ̀ náà lè máa ní ìtẹ̀síwájú, níwọ̀n ìgbà tí ó bá pa majẹmu ọba Babiloni mọ́. +Ṣugbọn ọba Juda ṣọ̀tẹ̀ sí ti Babiloni, ó rán ikọ̀ lọ sí Ijipti pé kí wọ́n fún òun ní ẹṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun. Ǹjẹ́ yóo ní àṣeyọrí? Ṣé ẹni tí ń ṣé irú èyí lè bọ́? Ṣé ó lè yẹ majẹmu náà kí ó sì bọ́ ninu rẹ̀? +“Èmi OLUWA fi ara mi búra pé, ní ilẹ̀ Babiloni, ní ilẹ̀ ọba tí ó fi í sórí oyè ọba tí kò náání, tí ó sì da majẹmu rẹ̀, níbẹ̀ ni yóo kú sí. +Farao, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati ọpọlọpọ eniyan rẹ̀, kò ní lè ràn án lọ́wọ́ nígbà ogun; nígbà tí ogun bá dótì í, tí wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ láti pa ọpọlọpọ eniyan. +Kò ní sá àsálà, nítorí pé kò náání ìbúra ó sì da majẹmu, ati pé ó ti tọwọ́ bọ ìwé, sibẹsibẹ, ó tún ṣe gbogbo nǹkan tí ó ṣe.” +Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Mo fi ara mi búra, n óo gbẹ̀san ìbúra mi tí kò náání lára rẹ̀, ati majẹmu mi tí ó dà. +“Ìwọ ọmọ eniyan, pa àlọ́ kan kí o sì fi òwe bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀. +N óo da àwọ̀n mi bò ó mọ́lẹ̀, pańpẹ́ mi yóo mú un, n óo sì mú un lọ sí Babiloni. Níbẹ̀ ni n óo ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ tí ó hù sí mi. +Idà ni wọn óo fi pa àwọn tí wọ́n bá sá lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀, a óo sì fọ́n àwọn tí wọ́n bá kù ká sí gbogbo ayé, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀.” +OLUWA Ọlọrun ní:“Èmi fúnra mi ni n óo mú ọ̀kan ninu ẹ̀ka kan ní ṣóńṣó igi Kedari gíga,n óo ṣẹ́ ẹ̀ka kan láti orí rẹ̀,n óo gbìn ín sí orí òkè gíga fíofío. +Lórí òkè gíga Israẹli ni n óo gbìn ín sí,kí ó lè yọ ẹ̀ka, kí ó so,kí ó sì di igi Kedari ńlá.Oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́ ni yóo máa gbé abẹ́ rẹ̀.Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóo pa ìtẹ́ sí abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀. +Gbogbo igi inú igbó yóo mọ̀ péèmi, OLUWA, ni èmi í sọ igi ńlá di kékeré,mà sì máa sọ igi kékeré di ńlá.Mà máa sọ igi tútù di gbígbẹ,má sì máa mú kí igi gbígbẹ pada rúwé.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.” +Wí fún wọn pé, OLUWA Ọlọrun ní idì ńlá kan wá sí Lẹbanoni, apá rẹ̀ tóbi, ìrù rẹ̀ sì gùn, ó sì ní ìyẹ́ aláràbarà. Ó bá bà lé ṣóńṣó orí igi kedari kan, +ó ṣẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ lórí, ó gbé e lọ sí ilẹ̀ àwọn oníṣòwò; ó fi sí ìlú àwọn tí ń ta ọjà. +Lẹ́yìn náà, ó mú ninu èso ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ kan tí ó lọ́ràá, ní ẹ̀bá odò. Ó gbìn ín bí wọn tíí gbin igi wilo. +Igi yìí hù, ó dàbí àjàrà tí kò ga, ṣugbọn tí ó tàn kálẹ̀. Ẹ̀ka rẹ̀ nà sọ́dọ̀ idì yìí lókè, ṣugbọn gbòǹgbò rẹ̀ kò kúrò níbi tí ó wà. Ó di àjàrà, ó yọ ẹ̀ka, ó sì rúwé. +“Idì ńlá mìíràn tún wà, apá rẹ̀ tóbi, ìyẹ́ rẹ̀ sì pọ̀ lọpọlọpọ. Àjàrà yìí bá kọ orí gbòǹgbò ati ẹ̀ka rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ idì ńlá yìí, kí Idì náà lè máa bomi rin ín. +Idì yìí bá hú u níbi tí wọ́n gbìn ín sí, ó lọ gbìn ín sí ilẹ̀ kan tí ó lọ́ràá lẹ́bàá odò, kí ó lè yọ ẹ̀ka, kí ó so èso, kí ó sì di àjàrà ńlá tí ó níyì. +“Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní kí o bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé àjàrà yìí yóo ṣe dáradára? Ṣé idì ti àkọ́kọ́ kò ní fa gbòǹgbò rẹ̀ tu, kí ó gé ẹ̀ka rẹ̀, kí àwọn ewé rẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ sì rọ?’ Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ nílò alágbára tabi ọ̀pọ̀ eniyan, láti fà á tu tigbòǹgbò tigbòǹgbò. +Òwe Nípa Àwọn Ẹyẹ Idì ati Àjàrà. +OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó bi mí pé: +“Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá bí ọmọ, tí ọmọ yìí ń fi ipá jalè, tí ń pa eniyan, tí kò ṣe ọ̀kankan ninu gbogbo ohun tí a kà sílẹ̀ pé baba ń ṣe, +ṣugbọn tí ó ń jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tí ó ń bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀; +tí ń ni talaka ati aláìní lára, tí ń fi ipá jalè, tí kì í dá ohun tí onígbèsè rẹ̀ bá fi ṣe ìdúró pada fún un, tí ń bọ oriṣa, tí ń ṣe ohun ìríra, +tí ń gba owó èlé; ǹjẹ́ irú eniyan bẹ́ẹ̀ lè yè? Kò lè yè rárá. Nítorí pé ó ti ṣe àwọn ohun ìríra wọnyi, yóo kú ni dájúdájú; lórí ara rẹ̀ sì ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà. +“Ṣugbọn bí eniyan burúkú yìí bá bí ọmọ, tí ọmọ yìí rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ń dá, tí ẹ̀rù bà á, tí kò sì ṣe bíi baba rẹ̀, +tí kì í jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tí kò bọ àwọn oriṣa ilé Israẹli, tí kò bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, +tí kò ṣẹ ẹnikẹ́ni; tí Kì í gba ohun ìdúró lọ́wọ́ onígbèsè, tí kì í fi ipá jalè, ṣugbọn tí ń fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí sì ń da aṣọ bo ẹni tí ó wà ní ìhòòhò, +tí ó yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀, tí kì í gba owó èlé, tí ń pa òfin mi mọ́, tí sì ń rìn ninu ìlànà mi, kò ní kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, dájúdájú yóo yè. +Baba rẹ̀ yóo kú ní tirẹ̀, nítorí pé ó ń fi ipá gbowó, ó ń ja arakunrin rẹ̀ lólè, ó sì ń ṣe ohun tí kò dára sí àwọn eniyan rẹ̀; nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ ni yóo ṣe kú. \ No newline at end of file