diff --git "a/yorubaCorpus/Ycorpus_0.txt" "b/yorubaCorpus/Ycorpus_0.txt" new file mode 100644--- /dev/null +++ "b/yorubaCorpus/Ycorpus_0.txt" @@ -0,0 +1 @@ +Adìẹ KFC kò dùn mọ́n! Ẹkú ọjọ́ mẹ́ta o ẹ̀yin ènìà pàtàkì wọ̀nyí. Ṣe dáradára ni mo bá gbogbo yín o? Ọ̀rọ̀ ọ t’òní á fẹ́ jọ yẹ̀yẹ́ létí ẹlòmíì, ṣùgbọ́n kìí ṣ’àwàdà rárá o. Ọ̀rọ̀ gidi ni. Ẹ ní kílódé? Ẹ mà ṣeun o. Ebi ló pa mí ní ìrọ̀lẹ́ òní tó mún mi ya ilé oúnjẹ olókìkí nì tí wọ́n ń pè ní KFC. Adìẹ díndín ni wọ́n ń tà níbẹ̀. ‘Tapátẹsẹ̀ ni wọ́n ń dín in. Tí ẹ bá fẹ́ jẹ ẹ́ ní ẹyọ-ẹyọ, ẹ lè rà á bẹ́ẹ̀. Bó sì jẹ́ àdàpọ̀ ẹsẹ̀ àti apá lẹ fẹ́, ìyẹn náà wà. Kódà wọn a tún máa ṣè’kan pẹlẹbẹ láti igbá-àyà adìẹ, wọ́n á tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ sí ààrin búrẹ́dì pẹ̀lú ẹ̀fọ́ díẹ̀ àti àwọn midinmíìdìn ní ọlọ́kanòjọ̀kan. Àwọn olóyìnbó a máa pè’yẹn ní “Burger”. Kiní ọ̀hún a máa wù’yàn jẹ o jàre. Àgàgà àwọn tí wọ́n fi ata sí dáadáa. Wọ́n tún ṣe’kan tó jọ dùndú anọ̀mọ́ tí wọ́n ń pè ní “fries”. Kiní ọ̀hún a máa dùn tí wọ́n bá dín in gbẹ dáadáa. Parí-parí ẹ̀, ènìà tún lè fi ọtí ẹlẹ́ridòdò kan lé e. Gbogbo rẹ̀ á wá ṣe rẹ́gí-rẹ́gí l’ọ́nà ikùn. Ara olúwarẹ̀ a wá yá gágá. Kí ló wá fa ẹjọ́ o Alákọ̀wé? Yó dára fún gbogbo yín o. Ṣé ẹ rí adìẹ KFC yíì, wọn ò kàn kí ń dín in lásán o. Wọ́n á kọ́kọ́ fi àwọn èròjà kan pa á lára kí wọ́n to sọ ọ́ sínú agbada òróró gbígbóná. Àwọn èròjà wọ̀n-ọn nì ní wọ́n fún oújẹ wọn ní adùn tó dára dé ibi pé, wọ́n sọ ọ́ ní ‘àjẹ-lá-ìka’ – ajẹ́pé ení bá jẹ adìẹ díndín wọn, ńṣe ni olúwarẹ̀ á máa lá ìka tó fi mún adìẹ náà sẹ́nu nígbà tó bá jẹ ẹ́ tán. Nítorí ìdí èyí, KFC di gbajúgbajà, wọ́n di ọ̀kan nínú àwọn ilé-oúnjẹ aláràjẹ tó lókìkí jù ní gbogbo àgbáyé. Tó bá jẹ́ lóòótọ́ ni àwọn èròjà náà dùn tó bẹ́ẹ̀, kí ló ṣe tí àwọn ilé-oúnjẹ ìyókù ò ṣe máa lò wọ́n se oúnjẹ tiwọn? Ìtàn ń bẹ níbẹ̀. Ṣé Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ‘bí kò bá ní ìdí, obìnrin ò kí ń jẹ́ Kúmólú’. Ìdí abájọ ni pé, gbogbo àwọn èròjà náà, àti ètò bí wọ́n ṣe ń pò wọ́ pọ̀, nǹkan àṣírí ńlá ni. Láti ọdún 1930 títí dé ọjó òní, awo ńlá ló jẹ́ láàrin wọn. Ẹnìkankan ò sì tí ì já wọn. Àmọ́ ṣá o, ṣé bí a bá gbìyànjú títí, tí a kò rí kókó tú, a ó fi kókó ọ̀hún sílẹ̀, a ó wàá okùn míì lọ? Ìyẹn ló dífá fún àwọn aládìẹ díndín ‘yòókù, tí wọ́n dẹ́kun fífarawé KFC, tí wọ́n sì wá àwọn èròjà tiwọn lọ. Ní tèmi o, mo ti jẹ adìẹ díndín níbòmíràn tọ́n dùn yùngbà dé’bi pé, ti KFC gangan ò dùn lẹ́nu mi mọ́n! Àgàgà lọ́dọ̀ àwọn ará Pakistan àti India. Wọn a máa fi ata sí oúnjẹ dáadáa bíi tiwa. Lónìí, mo yà KFC lọ nítorí ebi ni. Mo ra itan àti igbá-àyà adìẹ, pẹ̀lú àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ oújẹ kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú ife Pepsi tútù kan. Bí mo ṣe bù ú jẹ ni adìẹ náà kàn ṣ’ọ̀rá sìnkìn sí mi lẹ́nu. Kiní ọ̀hún ò tiẹ̀ ta rárá, ó wá rí ràṣì-ràṣì lẹ́nu. Nígbà tó ṣe mí bí ẹní fẹ́ bì, mo bá tọ́ pepsi díẹ̀ sẹ́nu. Pepsi náà dàbí èyí tí wọ́n ti ṣí sílẹ̀ látààná, kò tiẹ̀ ru rárá – ó kàn dà bí omi lásán. Èsùrẹ́ sì fẹ́ gbé mi. Mo yáa mọ̀’wọ̀n ara mi, mo dìde kúrò ni ìkọ̀ oújẹ wọn, mo gba Pizza Express kan tí ń bẹ ní ẹ̀bá ibẹ̀ lọ. Mò bẹ̀ wọ́n kí wọ́n bá mi rẹ́ ata rodo sórí Pizza mi o jàre. Wọ́n kúkú ti dámi mọ̀n níbẹ̀ pé jata-jata ni mo jẹ́. Èrò tèmi ni pé, bíótilẹ̀jẹ́pé ilé-iṣẹ́ KFC fi dá wa lójú pé àwọn ò tíì pààrọ̀ àwọn èròjà tí wọ́n ń fi s’óúnjẹ láti ọdún 1930, kiní ọ̀hún ò dùn lẹ́nu tèmi mọ́n o. Ó ṣeéṣe pé ahọ́n ọ̀n mi ló ti yí padà, nítorí lóòótọ́ ni kiní ọ̀hún dùn sí mi nígbà kan rí. Tàbí pé, irọ́ ni ilé-iṣẹ́ náà ń pa fún wa. Bí o ti wù kí ó rí, ẹ ò yó rí mi níbẹ̀ mọ́n láti òní lọ. Ẹ̀yin ńkọ́? Ǹjẹ́ ẹ ti jẹun ní KFC láìpẹ́ yìí bí? Báwo lẹ ṣe rí oúnjẹ wọn sí? Ẹ jẹ́ ká gbọ́ o, ẹ fèsì kalẹ̀ o. Toò, ó tún dìgbà kan ná o ẹ̀yin ẹ̀dá pàtàkì mi. Kí Olódùmarè dá wa sí o. Àṣe. Èkó Ẹ ǹlẹ́ o ẹ̀yin ẹ̀dá Ọlọ́run wọ̀nyí. Fún apá kẹfà Ìgbésí-ayé Alákọ̀wé, ẹ fìkàlẹ̀ lé e pẹ̀lú mi nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yìí. Ẹ jẹ́ ká dé Ìpínlẹ̀ Èkó, ká wòran díẹ̀. Ní gbogbo ìgbà, èmi a kúkú máa kan sáárá sí gómìnà Èkó àná – Alàgbà Raji Faṣọla. Iṣẹ́ ńlá ló ṣe. Àyípadà tó dé bá ìpínlẹ̀ yìí ò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá. Ó sì sọ Èkó di ibi àmúyangan – ibi iyì, ibi ẹ̀yẹ. Nígbà kan rí, èmi ò kí ń fẹ́ rìn tí ilẹ̀ bá ti ṣú. Àmọ́ lóde òní, ẹ̀rù ò ṣábà á ba’ni mọ́n. Ọpẹ́ ni f’Ólúwa fún àwọn àyípadà rere wọ̀nyí. A ò ní ri àpadà sí burúkú láí-láí o. Kí gómìnà òní yáa múra síṣẹ́ gidi-gaan ni. Ẹ ò jẹ́ ká dánu dúró ń’bẹ̀un bí? Wọ́n ní “ọ̀rọ̀ púpọ̀, irọ́ ní í mú wá”. Yoòbá káàbọ̀. A jẹ́ pé mo kí gbogbo yín kú ọdún titun o. Ọdúnnìí, á sàn wá s’ówó, sàn wá s’ọ́mọ, sàn wá sí àláfíà – tí í ṣe baálẹ̀ ọrọ̀. Àṣẹ. Agbègbè Waterloo Alákọ̀wé mo tún dé. Ní apá karùn-ún Ìgbésí-ayé Alákọ̀wé, ẹ jẹ́ ká yà sí agbègbè Waterloo, létí bèbè gúsù odò Thames, ní olú-ìlú Igilàńdì wa yìí. Ibi tí ọdún Kérésì ti ń lọ ni kẹlẹlẹ. Agbègbè yìí la ti lè rí ọ̀bìrìkìtì ńlá tí wọ́n ń pè ní ‘ojú Lọndọn’ – London Eye. London Eye tí wọ́n kọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì ẹ̀yẹ ọdún kẹgbẹ̀rúnkejì – ìyẹn ọdún márùndínlógún sẹ́yìn báyìí. Èròngbà àwọn t’ọ́n kọ́ ọ síbẹ̀ ni pé kó kàn wà níbẹ̀ fún bí ọdún kan sí méjì. Ṣùgbọ́n lónìí ó ti di bàbàrà, oun àtọ́kasí ní ilú Lọndọn o. Tí ẹ bá dé’bẹ̀ ẹ ó rí ìdí abájọ. Èro tó tò kalẹ̀ pé àwọn fẹ́ gùn ún ò l’óǹkà. Bẹ́ẹ̀ owó ni gbogbo wọn ó san, kìí ṣe ọ̀fẹ́. Onírúirú àwọn òṣèré ni wọ́n máa ń ṣeré l’óde ibẹ̀. Láti káàkiri àgbáyé sì ni wọ́n ti wá. Kódà láti Afirika pẹ̀lú. Oúnjẹ náà wà ní ọlọ́kanòjọ̀kan, bótilẹ̀jẹ́pé ìjẹkújẹ oní ṣúgà la rí jẹ lọ́jọ́ náà. Ńṣe ni sẹ́lẹ̀ru ṣọkọléètì ń ṣàn bí omi níbẹ̀. Toò, a tún ṣe t’òní o, ọpẹ́ ni fún Olódùmarè. Ìyókù tun di ẹ̀yìn ọdún ńlá. Kí Olúwa ṣọ́ wa jù’gbà náà lọ o. Ódàbọ̀. Afárá Lọndọn Pàtàkì ni afárá yìí jẹ́ ní Lọndọn. Àwọn ará Róòmù ni wọ́n kọ́kọ́ kọ́ afárá náà ní nkan bi 2,000 ọdún sẹ́yìn. Látìgbà náà, wọ́n ti tún un kọ́ lẹ́ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹ bámi dé agbègbè àyíká Lọndọn Bridge – ìgbádùn ń bẹ níbẹ̀. Níbi ìgbádùn bá sì wà, dandan ni kí ẹ bá èmi kinní yìí níbẹ̀ 🙂 Mo kí yín kú ìpalẹ̀mọ́ ọdún o. Ire owó, ire ọmọ, ire àláfíà tí í ṣe baálẹ̀ ọrọ̀. Ódìgbà kan ná. Abúlé Stratford Apá keta ti bà bí àdàbà o. Ẹ bámi dé abúlé kan ní Lọndọn tí wọ́n ń pè ní Stratford. Ibẹ̀ ni ìdíje Olympics ti ṣẹlẹ̀ ní ìdun-ùnta, ìyẹn l’ọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn. Ire o! Ilẹ̀-Ìyanu Ọ̀gìnìntìn Ìgbésí ayé Alákọ̀wé apá kejì ti bọ́ o. Ẹ bá mi dé Ilẹ̀-Ìyanu Ọ̀gìnìntìn tí ń bẹ nínú ọgbà ńlá Hyde Park. Ẹ má gbàgbé láti tẹ̀lé mi lórí YouTube o, kí n lè mọ̀n dájú pé ẹ ń gbádùn mi. Ṣé ẹ̀yin gbọ́rọ̀-gbọ́rọ̀ ni ọ̀gá àwa sọ̀rọ̀-sọ̀rọ̀. Ẹṣeun púpọ̀ o. Ààrin gbùngbùn Lọndọn Ètò titun látọwọ́ Alákọ̀wé. N ó máa mú yín káàkiri ìlú yìí kí ẹ lè rí ìgbésí ayé ọmọ Yoòbá nílẹ̀ yìí. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ lètò náà ó máa wáyé lórí ìkànnì YouTube mi, tàbí ní alakowe.com. Ètò kíní // Ìgbésí ayé Alákọ̀wé – Ààrin gbùngbùn Lọndọn // Ẹ bámi kálọ sí Piccadilly Circus, Leicester Square àti China Town. Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn Ṣé mo sọ níjọ́sí pé ìfẹ́ àfẹ́jù tí ń bẹ láàrin ọmọ ènìyàn àti ṣúgà bímọ. Bẹ́ẹ̀ ni o. Kódà ọmọ tí wọ́n bí ju ẹyọ kan ṣoṣo lo. Àwọn ọmọ náà ni Ààrùn, Àìsàn, Àìlera àti Àárẹ̀. Àwọn ọmọ wọ̀nyí a máa farahàn ní ìgbésí-ayé ẹ̀dá ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà àrà, wọn a sì máa da ọmọ-ènìyàn l’áàmú. Díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà àrà náà nìwọ̀nyí; Ẹ̀jẹ̀ Ríru, Ìfúnpá Gíga, Ìtọ̀ Ṣúgà, Wárápá, Àìsàn Ọkàn, Ọpọlọ Wíwú, Ojú Fífọ́, Ìdákọ́lẹ, Àpọ̀jù Ọ̀rá-Ẹ̀jẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Abí ẹ kò rí i pé àjẹjù ṣúgà kò dára fún ọmọ ènìyàn rárá bí? Ó yẹ ká yẹra fún un nígbà gbogbo, kí ó má baà ṣe àkóbá fún wa. Toò, ẹ jẹ́ ká fi man báhun lónìí nítorí pé “ṣókí l’ọbẹ̀ oge”. Èmi ni Alákọ̀wé yín ọ̀wọ́n. Ó tún dìgbà kan ná. Ènìyàn àti Ṣúgà Yoòbá ò purọ́ nígbà tó wípé “a kìí fi oyin sẹ́nu ká tutọ́”. Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ni, ó sì nítumọ̀ púpọ̀. Àmọ́ bó ti nítumọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ló ni ti eréfèé. Àdídùn tí ń bẹ nínú oyin dára púpọ̀, ó sì kún nkan tí ara ẹni ń fẹ́. Ẹlẹ́dàá ló ṣe ètò oyin ṣíṣe, tí Ó sì fi fún kòkòrò abìyẹ́ nì láti máa ṣe. Ní inú oje òdòdó ni kòkòrò oyin ti ń yọ àdídùn ṣe oyin. Nígbà tí mo wà ní kékeré, èmi àti ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi àti àwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń fẹ́nu fa oje òdòdó mun. A máa dùn lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣé áńgẹ́lì ọmọdé ni kò jẹ́ ka pàdé èyí tó máa pa wá lára. Nígbà míràn gan-an ńṣe la máa kúkú sọ odidi òdòdó sẹ́nu kàló, tí a ó rún un lẹ́nu wọ̀mù-wọ̀mù, tí a ó sì gbé e mìn gbùn-ún, tí nkankan ò sì ní ṣe wá. Bó ti wà láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé nìyẹn. Àwọn nkan tí Ẹlẹ́dàá ṣe, àwá ọmọ ènìyan pẹ̀lú, Ó ti fi ìbáṣepọ̀ sáàrin wa pé kí a jẹ́ aláànfàní arawa, kí a sì máa ṣe arawa lóore. Ìyẹn láàrin àwa ọmọ ènìyàn àti ẹranko gbogbo – ẹranko si ewéko, eweko sí ènìyàn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n àwa ọmọ ènìyàn a kìí yé kọjá àyè wa. A ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ tó ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àgbáyé yìí ò tẹ́ wa lọ́rùn o. A ní dandan àfi ká ṣe tí inú wa. A ní iṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ò dára tó, àfi ká tún un ṣe ní ìlànà tiwa. Àpẹrẹ ìwà yìí kan rèé; Ẹ̀dá ọmọ ènìyàn kọ̀ ó ní oyin ò dùn tó o. Ó tún wípe rárá, ìrèké náà kù díẹ̀ káàtó. A ní àfí ká ṣe ìwádìí nkan tó fa adùn inú àwọn nkan wọ̀nyí, kí a lè ṣe wọ́n ní ìlànà tiwa. Ọmọ ènìyàn bá fún omi inú ìrèké, ó gbé e raná ti omi náa fi gbẹ, tí ó fi ku kiní kan funfun báláhú. Kiní ọ̀hún jọ iyọ̀, àmọ́ dídùn rẹ̀ yàtọ̀ sí ti iyọ̀, ó jọ ti oyin àti ìrèké. Ẹ̀dá ọmọ ènìyàn ní “Kò tán bí!? A ti rí ìdí abájọ, ojú ti ẹ̀yin ọmọ kòkòrò!”. Ọmọ ènìyàn wo kiní ọ̀hún títí ó ní “Ṣúgà la ó máa pè ọ́” Ṣúgà amáyé dùn Ìwọ ni gan-an ajẹmáleètu Àdídù inú oyin abara funfun Àní ìwọ gan-an lọ dùn jù Ìwọ ni ìrèké gbóríyìn fún Àwọ̀ àlà rẹ ń wọ̀ mí lójú Láti ìgbà yìí ni ọmọ èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ń tọ́ kiní funfun ọ̀hún sí gbogbo nkan jíjẹ àti mímu. Wọn a máa tọ́ ṣúgà sí omi. Wọn a máa tọ́ ọ sí ẹ̀kọ mímu. Kódà àwọn kan a máa lá a ní gbẹrẹfu. Àwọn àgbàlagbà Yorùbá ti parí ọ̀rọ̀ tipẹ́-tipẹ́. Wọ́n ní “Àṣejù ni bábá àṣetẹ́”. Ọ̀rọ̀ àgbà rèé, kì báà pẹ́, a máa padà ṣẹ nígbẹ̀yìn ni. Nígbà tó yá, ifẹ́ àfẹ́jù tí ń bẹ láàrin ọmọ ènìyàn àti ṣúgà bá bímọ. Ìfẹ́ ọ̀hún ni àṣejù. Ọmọ náà ni àṣetẹ́. Kí wá ló ṣẹlẹ̀? N ó fi tó o yín létí láìpẹ́. Ẹ padà wá gbọ́ àbọ̀ ọ̀rọ̀. Ẹ ṣeun, mò ń bọ̀ ná. Ìtẹ̀wé Yorùbá titun gbòde Ẹ ǹlẹ́ o ẹ̀yin tèmi. Ó tójọ́ mẹ́ta kan. Ǹjẹ́ ẹ rántí ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta sẹ́hìn, mo ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí a lè gbà kọ èdè Yorùbá pẹ̀lú àmì lórí àwọn ẹ̀rọ wa. Ọ̀nà titun kan ti balẹ̀ wàyí o! Yorubaname.com ni wọ́n fún wa ní ẹ̀bùn yí ní ọ̀fẹ́. Mo ti ń ṣe àmúlò ìtẹ̀wé yìí ní kété tó jáde, kí n lè fún un yín lábọ̀ nípa rẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Bíótilẹ̀jẹ́pé ó ṣòro ó lò lákọ̀ọ́kọ́, nítorí kò mọ́n mi lára, kò pẹ́ náà tó fi mọ́nra. Kódà, òun ni mò ń lò lọ́wọ́ báyìí. Díẹ̀ nínú àwọn àǹfàní tọ́n hàn sí mi nìwọ̀nyí: 1. Àyè àti fi àmì sí ‘n’ àti ‘m’ ( ǹ ń, m̀ ḿ ) 2. Ó ń ṣiṣẹ́ lórí Windows àti Mac 3. Kò l’áàńsí lórí Ayélujára láti ṣiṣẹ́ 4. Ó rọrùn láti lò púpọ̀ ju àwọn ìyókù lọ, tí ó bá ti móni lára tán. 5. Ọ̀fẹ́ ni! Ajẹ́pé ẹ jẹ́ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Yorubaname.com fún akitiyan ńlá yìí. Ó dámi lójú pé èyí kò ní ṣe àṣemọn wọn o. Lágbára Èdùmàrè. Ata ju ata lọ Ẹ wá wo orí ológbò látẹ o ẹ̀yin èèyàn mi! “Èwo lẹ tún rí o Alákọ̀wé?” Yó yẹ yín kalẹ́! Mo mà tún rí nkan o. Lóòótọ́ àwa ọmọ Nàìjá a fẹ́ran ata, àgàgà àwa ti ilẹ̀ Oòduà. Ẹlòmíì a se’bẹ̀, a fi ata já a. Kódà a rí ẹni tí kò ní jẹun kankan àfi tí ata bá wà níbẹ̀. Dájú-dájú ìran jata-jata ni àwa ń ṣe. Òun ni mo fi ń yangàn fún àwọn ọ̀rẹ mi kan nílẹ̀ yìí o. Mo wí fún wọn pé kòsí oúnjẹ kankan nílẹ̀ wọn tó láta to tiwa. Mo tún ṣakọ pé irúfẹ́ ata tí èmi Alákọ̀wé ò lè jẹ – wọn kò tí ì ṣẹ̀dá ẹ̀ nílẹ̀ yìí. Àwọn òyìnbó dá mi lóhùn pé òtítọ pọ́nbélé ni mo sọ, n kò parọ́ rárá.   Wọ́n tún wípé kódà àwọn aláwọ̀ funfun tí mo rí yìí – tí àwọn bá ṣèṣì jẹ irú ata tí a ń wí yìí, ńṣe ni ojú àwọn á di pípọ́n kuku bí aṣọ àparò! Bẹ́ẹ̀náàni gbogbo ọ̀nàfun á máa ta àwọn bí ẹní máa kú ni. Wọ́n ní nítorí ìdí èyí ni àwọn kò ṣe kí ń jẹ ata. Pé tí oúnjẹ bá ti láta fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ báyìí, àwọn a yáa yẹra fún un.  Mo rín ẹ̀rín àrínbomilójú nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí tán. Kání àwọn babańlá wa mọ̀n níjọ́ kìíní àná ni, bóyá àwọn Gẹ̀ẹ́sì ò bá tí múnwa sìn. Mo bá tún mú ìpanu aláta kan tí mo múdání, mo sọ ọ́ sẹ́nu kàló, mo rún un lẹ́nu wómú-wómú. Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹgbẹ́ mi aláwọ̀funfun náà. Wọn gbóríyìn fún mi, wọ́n wa ń wo èmi Alákọ̀wé gẹ́gẹ́ bí òrìṣà kan láàrin wọn. Ní òjijì ni ẹnìkan bá dìde láàrin wọn. Ọmọ orílẹ̀èdè Ṣáínà ni onítọ̀hún ń ṣe. Jin ni orúkọ rẹ̀, èmi àti arákùrin náà sì ti mọ̀nrawa fún nkan bí ọdún kàn nípasẹ̀ iṣẹ́ òòjọ́ wa. Jin bá bọ̀ bí ẹní pòwe. Ó ní “ní ìlú afọ́jú, olójúkan ni ọba wọn”. Ẹ gbà mí o! Ta wa ló fún ará Ṣáínà lẹ́nu ọ̀rọ̀? Èmi náà bá dá lóhùn pé njẹ́ ó mọ̀n pé ṣàkì kìí ṣẹgbẹ́ ọ̀rá bí? Mo nawọ́ ìpanu aláta tí mo ń jẹ sí i – “ó dáa náà gbà èyí kí o tọ́ ọ wò. Ṣé tí ogún ẹ̀ni bá dáni lójú a fi ń gbárí ni?” Jin kúkú kọ̀ ó l’óun ò jẹ ìpanu aláta. Ó ní kékeré nìyẹn. Kàkà kí ó jẹ, òwe ló tún pa. Ó tẹnu bọ̀rọ̀ ó wí pé “Àìrìnjìnnà làìrí abuké ọ̀kẹ́rẹ́, tí a bá rìn jìnnà á ó rí abuké erin. N ó mú ìrẹ Alákọ̀wé dé ibi tí wọ́n ti ń jẹ ata gidi nílẹ̀ yìí, ìwọ yíò sì gba Ọlọ́run l’ọ́gàá! Ìwọ á gbà pé àti ṣàkì o, àti ọ̀rá o, ẹran abọ́dìí ni ọba gbogbo wọn” Mo wí fún Jin pé tó bá rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ kó nìṣó níbẹ̀. Mo fọwọ́ sọ̀yà pé irúkírú oúnjẹ alátá tí wọ́n bá sè fún mi níbẹ̀, èmi Alákọ̀wé á jẹ ẹ́ láì mu omi kankan sí i. Ẹbá ọ̀nà kékeré kan ní àdúgbò kọ́lọ́fín kan láàrìn gbùgbùn ilú Lọndọn ni ilé-oúnjẹ náà sápamọ́ sí. Orúkọ rẹ̀ ni Chilli Cool. Orúkọ ọ̀hún sì fẹ́ dá’yà já’ni. Ata rodo ní ń jẹ́ Chilli. Àmọ́ ẹ̀rù ò b’odò, ibi líle làá ba ọkùnrin. A wọlé a fi ìkàlẹ̀ lé e. Ìgbà náà ni Jin wí fún mi pé kí n má wùlẹ̀ wo ìwé-oúnjẹ́ tí wọn fún wa. Pé òun Jin ni yó yan gbogbo nkan tí màá jẹ. O ní ṣé mo rántí nkan tí mo sọ? “Tí ìwọ bá lè jẹun láì mu omi lóòótọ́, èmi Jin ọmọ ilẹ̀ Yiwu ní Ṣáínà ni yíò sanwó. Ṣùgbọ́n tí ìwọ Alákọ̀wé Yoòbá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ajẹ́pé mo rí oúnjẹ ọ̀fẹ́ jẹ nìyẹn nítorí ìwọ ni wàá tọwọ́ bọ àpò o”. Èmi náà bá dá a lóhùn pé mo fara mọ́n ọn bẹ́ẹ̀. “Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, oun tó bá yá kìí tún pẹ́ mọ́n, oúnjẹ ọ̀hún dà? Ẹ gbé e jáde kí n máa báṣẹ́ lọ jàre!” Nígbà tó yá ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ń gbóòórùn nkan tó ń tasánsán bí ọbẹ̀ ata. Kíà ni wọ́n bá gbé àwọn oúnjẹ ọ̀hún wá lọ́kọ̀ọ̀kan. Ni nkan bá ṣe! Ẹ wá wo ata ní onírúirú, ọlọ́kanòjọ̀kan àti oríṣìíríṣìí! Gbogbo irúfẹ́ ata tí Olódùmarè dá sí ilé-ayé ni wọ́n péjọ sínú àwo. Gbogbo wọn wá ń játùbú nínú omi ata, wọ́n ṣe àwọ̀ kàlákìní. Ẹ̀rù Ọlọ́run sì bà mí. Oúnjẹ rèé àbí àtẹ aláta? Jin rẹ́rìn-ín músẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun lọ. “Óyá Alákọ̀wé oúnjẹ yá, àbí bóo ni?” Mo kúkú gbìyànjú ẹ̀. Mo fi ṣíbí tọ́ díẹ̀ sẹ́nu, ni òógùn bá bò mí, ahọ́n mi ṣe bí ẹní fẹ́ bó. “Omí o!” Pàtàkì Ìwé Kíkọ Àti Kíkà Ní Èdè Abínibí Oun tí a ní là ń náání. Àwọn àgbà Yorùbá ni wọ́n wí bẹ́ẹ̀. Njẹ́ ní òde òni àwa ọmọ Odùduwà ń náání oun tiwa bí? Ọ̀rọ̀ ọ́ pọ̀ níbẹ̀ o ẹ̀yin ará mi. Ó dáa ẹ jẹ́ ká mú’kan níbẹ̀ ká gbé e yẹ̀wò. Bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀ ni kò fẹ́ràn láti máa sọ èdè Yorùbá lẹ́nu mọ́n, dájú-dájú púpọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí gbọ́ ọ l’ágbọ̀ọ́yé, wọn kò kàn kí ń sọ ọ́ ni. Lára àwọn agbọ́másọ wọ̀nyí, bóyá la lè rí ìkankan nínú wọn tó mọn èdè Yorùbá kà dáradára, ká tilẹ̀ má sọ̀rọ̀ ọ kíkọ. Àgàgà tí a bá fi àmì sọ́rọ̀, a máa fa ìrújú fún púpọ̀ nínú wọn. Ó mú mi rántí nkan tí ẹnìkan wí lóri Twitter níjọ́sí. Ó ní Yorùbá kíkọ̀ èmi Alákọ̀wé fẹ́ jọ èdè Lárúbáwá lójú òun nítorí àwọn àmì ọ̀rọ̀ tí mo máa ń fi sí i. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún pa mí ní ẹ̀rin lọ́jọ́ náà kì í ṣe díẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ burúkú òhun ẹ̀rín kọ́ rèé ni ẹ̀yin èèyàn mi? À á ti wá gbọ́? Ṣé ẹ rí ibi tí ọmọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí nípà èdè Gẹ̀ẹ́sì kíkọ? Ótì o! Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àbí ẹ rí ibi tí ọmọ Ilẹ̀ Faransé ti ń ránmú sọ Faransé bí? Èmi ò rí i rí o. Kí ló wá fà á? Ìkíní ni pé l’óòótọ́ a kò ní ètò ìkọ̀wésílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá kí àwọn Lárúbáwá àti àwọn ará Úróòpù tó dé. Ajẹ́pé kò sí nínú àṣà wa láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Àtẹnudẹ́nu àtìrandéran ni àwá ń ṣe ní àtètèkọ́ṣe. Ṣùgbọ́n ayé àtijọ́ nìyẹn o. Ayé ń lọ, à ń tọ̀ ọ́ ni. Èdè Yorùbá ti di kíkọsílẹ̀ ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn aṣíwájú èdè káàkiri Afirika nípa kíkọsílẹ̀. Ìkejì ni pé àwa ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Káàárọ̀oòjíire ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ pátápátá. Kódà, àfi bí ẹni pé ẹlòmíràn kórira èdè abínibí tirẹ̀ gan-an ni. Nítorí ìdí èyí a kì í ṣe àmúlò èdè Yorùbá fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ile-ìwé wa, tàbí fún ìjírórò l’áwùjọ òṣèlú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Yorùbá ń parun lọ kọ́ yìí? Àbí kí ni ọ̀nà àbáyọ? Àwọ̀n àgbà Gẹ̀ẹ́sì bọ̀ wọ́n ní “Ìrìnàjò ńlá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbésẹ̀ kan ṣoṣo”. Gẹ̀ẹ́sì káàbọ̀ o jàre. Ọgbọ́n àgbà ń bẹ lọ́dọ̀ tiwọn náà. Ajẹ́pé Yoòbá gbọ́n Èèbó gbọ́n ni wọ́n fi dá ilẹ̀ London 🙂 Ká tiẹ̀ pa àwàdà tì. Kíni irúfẹ́ ìgbésẹ̀ kíní tó bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ńlá ìsọ́jí èdè Yorùbá kíkọ àti kíkà? Toò, ìyẹn dọwọ́ olúkúlùkù wa. Láyé òde òní gbogbo wa ni ònkọ̀wé níwọ̀n ara tiwa. Yálà lórí ẹ̀rọ ojútáyé nì tí a mọ̀n sí Facebook, tàbí àwùjọ ẹjọ́wẹ́wẹ́ nì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Twitter. Kíní ṣe tí àwa ò máa ṣe àmúlò èdè wa lórí àwọn àwùjọ wọ̀nyí déédé. Lóòótọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ló pabambarì káàkiri àgbàyé, àmọ́ a láti gbé èdè tiwa náà lárugẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ibòmíràn ṣe máa ń ṣe. Toò, ọ̀rọ̀ mi ò jù báyìí lọ. Ṣé wọ́n ní “ọ̀rọ̀ púpọ̀, irọ́ ní í mú wá” Tó tó ṣe bí òwe. Ìpàdé wa bí oyin o. Ẹkú Ọdún Kérésìmesì Alákọ̀wé ti gba òmìnira kúro ní Ẹ súré tete lọ sí Ire o! Ebola Mo kí gbogbo yín o. Ẹ kú ọjọ́ mẹ́ta. Ẹ sì kú àìfaraálẹ̀ náà. Olúwa yó máa fúnwa ní alékún okun àti agbára o. Toò, ọ̀rọ̀ ló kó mokó morò wá. Èé ti rí? Ọ̀rọ̀ Ebola yìí mà ni o. Kòkòrò búburú tí í fa àjàkálẹ̀ ààrùn. Kòkòrò tí kò gbóògùn. Bóo la ti wá fẹ́ ṣe é o? Ibo là á gbe gbà? Àwọn oní Bókobòko níwá, Èbólà lẹ́hìn. Àfi kí Elédùà kówa yọ. Àmọ́ ṣá, Yoòbá ti wípé ojú l’alákàn fi ń ṣọ́rí. Kí oníkálukú yáa tẹra mọ́n ètò ìmọ́ntótó rẹ̀. Kí ó sì máa ṣe àkíyèsí gbogbo nkan tí ń lọ ní’tòsí. Orísìírísìí là ń gbọ́ nípa kí la lè ṣe láti dáàbò bo’ra ẹni. Àwọn kan ní omi gbígbóná àti iyọ̀ ni ká fi wẹ̀. Kíá ni àti mùsùlùmí àti kìrìstẹ́nì ń da omígbóná ságbárí. A tún gbọ́ pé orógbó tàbí obì ni àjẹsára tọ́n lè báni yẹra fún ààrùn Ebola. Wéré ni tọ́mọ́ndé tàgbà ń rún orógbó lẹ́nu bí i gúgúrú, tí wọ́n sì ń jẹ obì bí ẹní jẹ̀pà. Àt’orógbó àt’obì o, wọn ò ṣé rà lọ́jà mọ́n, ńṣe ni wọ́n gbówó lérí tete. Bẹ́ẹ̀ rèé ènìyàn ò báà bẹ́ sínú àmù ọmígbóná oníyọ̀, kó jẹ́ orógbó agbọ̀n kan, kó sì jẹ obì tó kún apẹ̀rẹ̀. Tí olúwarẹ̀ bá ko Ebola, tí kò bá ṣe àfira wá nkan ṣe, ṣàngbà fọ́ nìyẹn – ó di gbére. Èmi wí tèmi, àmọ́ ẹnu ọlọ́rọ̀ lọ̀rọ̀ ti ń dùn. Ẹ fetí sí ètò Yorùbá Gbòde níbi tí olóòtú Ṣọla Yusuf ti gba amòye onímọ̀ nípa Ebola, tí wọ́n sì làwá lọ́yẹ̀ dáadáa. Ẹ máa ṣe pẹ̀lẹ́-pẹ̀lẹ́ o. Ìpàdé wa bí oyin o. Ire o. Igbó Funfun – Apá kẹta Ìrìnkèrindò Moravia Mo kúkú tẹnu mọ́n ọn pé Oníyanu ni Ọlọ́run. Nípa ìṣẹ̀dá ọmọ ènìyàn, Ó ṣ’èkan ní dúdú aró, ọ̀kan funfun gbòò bí aṣọ àlà. Ẹlòmíì a pọ́n kuku bí aṣọ àparò, Elédùà ló ní kó máa rí bẹ́ẹ̀. Njẹ́ Aṣèyíṣèmíì ni Ọlọ́run. Nípa ìṣẹ̀dá igi inú igbó, Ọba Lókè tún dá a bí àrà ọ̀tọ̀. Èyí tó kúrú, èyí tó ga, gbogbo wọn n’ọ́n péjọ sínú igbo, tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára Ẹlẹ́dàá wọn. Òmíì fífẹ̀ gbàràgàdà bí igi osè tó tan gbòngbò kálẹ̀ káàkiri. Àwọn wọ̀nyí kìí ṣábàá ga lọ títí. Yoòbá bọ̀ ó ni “Ẹni bá máa ga, ẹsẹ̀ rẹ̀ yó tínrín” èyí ló dífá fún igi ọ̀pẹ́ nínú igbó. Ẹ jẹ́ ká fi ìyẹn sílẹ̀ ná. Alákọ̀wé Yorùbá, ẹni Olú Ọ̀run dá lọ́lá, mo dé ibi igbó nì tí wọ́n ń pè ní Igbó Funfun. Mo rí iṣẹ́ Ọlọ́run Ọba. Ẹ ní kíni mo rí? Yó yẹ yín o. Ní ọ̀nà àbáwọ igbó náà, àwọn arúgbó igi tò síbẹ̀ wàlàhìhì. Ìtàn fi yé wa pé àwọn igi náà ti wà níbẹ̀ láti ayé-báyé ni. Àwọ̀ wọn jẹ́ funfun nini, wọn kò sì ní ewé kankan lórí rárá. Wọ́n ní àwọn igi náà ti wà níbẹ̀ fún bíi ọgọ́rùn-ún mélòóka ọdún. Àgbà igi gbáà ni wọ́n. Igi funfun eléyìí ní tirẹ̀ mọn’rarẹ̀ lágbà. Kò ṣèṣe adìẹ funfun o. Bí atẹ́gùn ṣe ń fẹ́ ni àwọn igi náà ń fì sọ́tùn-ún sósì pẹ̀lú ẹ̀lẹ̀. Ṣé pẹ̀lẹ́-pẹ̀lẹ́ ni ìṣe àgbà, òun ni ijó ọba. Bẹ́ẹ̀ náà ni nkan tó jọ ohùn kẹ́lẹ́-kẹ́lẹ́ a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn igi náà wá. Á wá dàbí pé wọ́n ń kíni káàbọ̀ sí inú igbó àwọn. Tí èèyàn bá kọ́kọ́ wọnú igbó náà, yó rí àpẹrẹ pé ọkọ̀ a máa rin ọ̀nà tó wọnú igbó náà lọ. Ọ̀nà náà tẹ́jú pẹrẹsẹ, ó sì wọnú igbó náà lọ tààrà. Àmì ìkìlọ̀ kan ń bẹ níbẹ̀ tó wípe “Ìwọ máṣẹ yà kúrò lójú ọ̀ná yìí títí tí ìwọ yó ṣe tọ igbó yìí já o!”. Èyí ṣẹ̀rù bani díẹ̀. Mo yáa tẹsẹ̀ mọ́nrìn ní tèmi, èmi adúláwọ̀ tòótọ́ 🙂 Lọ́gán tí mo wọnú igbó náà ni mo ṣàkíyèsí i pé àwọn igi ibẹ̀ ti pàwọ̀dà, wọn kò jẹ́ funfun mọ́n. Wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í léwé kọ̀ọ̀kan lára, bíótilẹ̀jẹ́pé irúfẹ́ igi kannáà ni àwọn pẹ̀lú àwọn funfun ti iwájú igbó náà. Ìdí ẹ̀ ni pé àwọn igi abẹwélórí wọ̀nyí ò tíì di arúgbó igi. Ojọ́-orí àwọn igi wònyí ò tíì ju nkan bíi ọgọ́rùn-ún kan ọdún lọ. A jẹ́ pé àwọn ò tíì pá lórí, wọn kò tíì h’ewú lára. Àṣé ìṣe ènìyà náà ni ìṣe igi níbìkan. Ọlọ́run tóbi. Nígbà tó yá mo bá tún dé ibìkan tó dàbí ilẹ̀ olókùúta bákan. Àwọn igi tó hù níbẹ̀, ńṣẹ ni gbòngbò wọn lọ́pọ̀ mọ́n òkúta. Ọ̀kan ló tiẹ̀ ṣemí bí ẹ̀rín bí ẹ̀rù o. Lábẹ́ igi kan, ilẹ̀ ṣe bí orí ènìyàn kan tó lanu bí ẹní kọrin. Ó kọ́kọ́ bàmí lẹ́rù ná, ṣùgbọ́n ó tún pamí ní ẹ̀rín nígbà tó múnmi rántí orin tí olóòtú ètò Tiwa’n’tiwa Alàgbà Oyèkúnlé Azeez máa ń kọ lẹ́ẹ̀kọ̀kan. “♫ òkúta òde, gbòngbò òde, ♪ ẹ bùnwa lóde lò ò..♫ Ẹ̀rín náà ni mò ń rín tí mo fi tọ igbó náà já sí pápá kan. Bí mo ti jáde ni mò rí àwọn ẹranko méjì kan tí wọn jọ irúfẹ́ ẹṣin kan. Èyí ló fi mí lọ́kàn balẹ̀ gbáà pé ibi a wí la dé yìí o. Oko àgbẹ̀ tí mo dé tì ni mo já sí lágá. Ọlọ́run ló bámi ṣé kìí ṣèèyàn. Bí arákùnrin àgbẹ̀ náa ti rí mi ló súré tete tọ̀ mí wá, a wá jọ pasẹ̀pọ̀ dé ibi abà rẹ̀. Ajá rẹ̀ náà ń gbọ̀nrù tẹ̀lé wa. A kí arawa ní èdè wọn. Ṣé ẹ mọ̀n pé èmí kinni yìí agbédè-gbẹ́yọ̀ ni mí. Olúmọ̀nọ́nrìn náà ni mí pẹ̀lú. Gbàrà tí a wọ abà náà ni oúnjẹ́ ṣetán àti jẹ. Ṣé Yorùbá ti kúkú ní “a kìí lẹ́ni ní mọsàn ká mun kíkan’. Orí Yoòbá ti pé tipẹ́ o jàre 🙂 Ẹ ṣeun o ẹ̀yin ènìyàn rere wọ̀nyí. Ẹ kú àtìlẹ́hìn mi. Olúwa á gbé yín ga o. Tí ẹ bá gbádùn àwọn ìtàn mi, ẹ má ṣàìfi èsì sílẹ̀ fún mi. Tàbí kí ẹ tẹ̀lé mí ní Bẹ́ẹ̀ náà ẹ lè fìwé ránṣẹ́ sí mi ní Ẹ padà wá láìpẹ́ fún àwọn àròkọ kan t’ọ́n ń bọ̀ lọ́nà. Nkan ń bẹ ẹ̀yin ọmọ ènìyàn! Yàrá Inú Òfurufú – àpá kejì Ìrìnkèrindò Moravia Àwámárìídìí ni Ọlọ́run Ọba. Ẹlẹ́dàá tó dá ayé òun ọ̀run. Alágbára ńlá tó dá àwa ọmọ ènìyàn sórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àgbáyé. Òun náà ló tẹ́ òfurufú léwa lórí. Olódùmarè ló pa á láṣẹ fún òbìrìkìtì ayé kó máa yí oòrùn po láìdúró. Kí ìyípo kan máa jẹ́ ọdún kan. Àní sẹ́, Elédùà Apàṣẹwàá ló ní kí ayé gan-an máa pòyì ararẹ̀. Kí ìpòyì kan máa jẹ́ ọjọ́ kan. Àsẹ Ẹlẹ́dàá ni. Èdùmàrè tó dá ẹ̀dá ọmọ èèyàn tó pàṣẹ pé ká máa bí síi ká sì máa rẹ̀ síi, Òun náa ló ṣe ọpọlọ ọmọ ènìyàn yàtọ̀ sí ti ẹranko lásán. Ó wípé bí ọjọ́ ṣe ń yí lé ọjọ́, tí oṣù ń yí l’óṣù, tí ọdún yí l’ọ́dún, kí ọpọlọ wá náà máa gbòòrò síi. Àlékún ọgbọ́n, àlékún ìmọ̀, àlékún òye ọmọ ènìyàn láti ìrandéran ti mú ìlọsíwájú kànkà bá àwa ọmọ ènìyàn gbáà. Ẹ̀yà ẹranko kan kò jẹ́ rí àwa ọmọ ènìyàn fín, àyàfi tó bá ń wa àbùkù òun ìparun. Àwa ẹ̀dá ọmọ aráyé, a wá dúró gẹ́gẹ́ bí kábiíòsí láàrin gbogbo àwọn ẹ̀dá tí Olódùmarè dá sí ilé-ayé. Olódùmarè gbàwá láàyè yìí ká máa dárà bó ti wù wá ní ilé ayé. Kódà àgbára àti làákáyè àwá ọmọ ènìyàn ti gá dé’bi pé àwọn mìíran a máa sọ pé kòsí Ọlọrun, pé àwa gan-an là ń bẹ ní ìdí orò. A ṣe títí a kọ́lé gíga roro bí ẹni pé kí àwa ọmọ ènìyàn gan-an lọ máa fi ojú-ọ̀run ṣe ibùgbé. Ṣèbí àwa gangan ni ẹlẹ́dàá? Ṣùgbọ́n o, Ṣèyíówùú Ọlọ́run kìí ṣe àìfagbára rẹ̀ han ọmọ ènìyàn lẹ́kọ̀kan. Njẹ́ ìwọ kọ́le gíga sókè réré? Kú iṣẹ́ ńlá ìwọ ọmọ ènìyàn, kú u làálàá. Èmi Olódùmarè ma sì rọ òjò lé e, ma fẹ́ ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ lé e, ma fi ìkúùkù òjò bò ó mọ́nlẹ̀, ma ṣán an ní àrá ṣààràrà, bẹ́ẹ̀ náà ma sì fa òṣùmàrè pálapàla sí iwájú rẹ̀. Ma ṣe gbogbo èyí láàrin ìṣẹ́jú kan péré. Nígbàtí ìwọ Alákọ̀wé bá gbójú wòkè wo ilé gogoro ńlá nì, tí ìwọ ń gbóríyìn fún àwọn ọmọ ènìyàn tí wọ́n kọ́ irúfẹ́ ilé àràmàndà yìí, tí o rò pé nkan ìyanu ni, Èmi Ẹlẹ́dàá rẹ̀, N ó tan ìmọ́nlẹ̀ oòrùn lókè, tí ògo tirẹ̀ yíò borí ògo ilé gogoro náà, tí ìwọ yíò sì mọ̀n dájú pé Tèmi ni iyì gbogbo, Tèmi ni ìyanu, nítorí agbára Tèmi ju ti ọmọ ènìyàn lọ. Ìwọ Alákọ̀wé ti mo fi èdè Yoòbá ta lọ́rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn, o yíò mọ̀n pé Èmi Olódùmarè ni Ẹlẹ́dàá gbogbo nkan. Bí gbogbo rẹ̀ se ṣẹlẹ̀ gan-an lẹ gbọ́ ní ṣókí yẹn. Nígbàtí mo dé iwájú ilé gogoro náà, tí mo rí bó ṣe ga tó, kàkà kí n yin ọmọ ènìyàn, Elédùà ni mo kí kú iṣẹ́ ìyanu. Toò, Yoòbá ní oun tó bá yá kìí tún pẹ́ mọ́n. Kíákíá mo darapọ̀ mọ́n àwọn èrò níbẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ sí í gun àwọn pẹ̀tẹ́ẹ̀sì lọ́kọ̀kan láti àbáwọlé ilé náà títí dé yàrá ńlá kan. Níbẹ̀ ni àwọn èrò ti tò láti gun àkàsọ̀ afẹ̀rọfà tí ń gbéni lọ sókè nítorí ilé ọ̀hún ga tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, kò ṣé fẹsẹ̀ lásán gùn dé òkè. Nígbàtí a dé òkè tán, yàrá ńlá mìíràn la tún bọ́ sí. Yàrá náà ni àwọn fèrèsé fífẹ̀ tọ́n fúnni láàfàní láti wo ìta. Ìran tí gbogbo wá fẹ́ wò náà nìyẹn, nítorí láti ibẹ̀ ènìyàn á máa wo ilẹ̀ lókèrè. Gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń rìn nílẹ̀ á wa dàbí i kòkòrò kékèké. Àmọ́n kò tán níbẹ̀ o. Ó tún ṣeéṣe láti lọ sókè síi ṣùgọ́n ẹni ba fẹ́ débẹ̀, ẹsẹ̀ lásán ni yó fi gun àwọn àkàsọ̀ fún bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Àtàrí àjànàkú ni wọ́n pè é fún wa, wọn ní kìí ṣe ẹrù ọmọdé o. Njẹ́ ẹ mọ̀n pé kòsí ẹni fẹ́ lọ. Bí ojú ṣe ro ẹnìkan ni ẹ̀rù ba ẹlòmíì. Àyàfi Alákọ̀wé yín àtàtà. Ṣé ẹ ti mọ̀n tẹ́lẹ̀ pé ọkùrin mẹ́ta ni mí? Ìwájú ni irúfẹ́ wa fi ń gbọta, àwa kìí ṣojo ní ìran wa rárá. Mo ní kí wọ́n ṣílẹ̀kùn fún mi kí n máa gùn’kè lọ. Èmi fẹ́ gùn ún dókè pátápátá. Nígbà tó yá mo kúkú dé òkè pátápátá bíótilẹ̀jẹ́pé ńṣe ni mò ń mín hẹlẹhẹlẹ lọ. Yàrá tí mo já sí jọ èyí tí mo tí ń bọ̀, àmọ́ ó kéré jù ú lọ. Èmi nìkan ni mo dá wà níbẹ̀. Ibi tí ilé náà ga dé, nígbàtí mo bojú wo ìta níbi fèrèsé, mo wá ń wo àwọn ìkúùkù òjò láti òkè wọ́n. N kò le rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń rìn nílẹ̀ mọ́n nítori mo ti jìnnà sókè jù. Ó dàbí ẹni pé mo wà nínú ọkọ̀ òfurufú ni. Atẹ́gùn ń gbé àwọn ìkúùkù funfun kọjá bí èéfín, mo sì rí òjiji ilé gogoro náà tó fà lé àwọn ìkúùkù ojo náà. Kódà, nkan ìyanu gidi ni. Àmọ́ nígbàtí mo fẹ́ máa padà lọ sílẹ̀, ni nkan tó jọmí lójú jùlọ ṣẹl���̀. Òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Ṣùgbọ́n èmi ń wò ó láti òkè, ó ń rọ̀ nísàlẹ̀ lé àwọn tó wà nílẹ̀ lórí. Oòrùn ló ràn lókè ọ̀dọ̀ tèmi. Nkan àràmàndà méèrírí gan-an ni. Kò ṣeé ṣàpèjúwèé dáadáa láìfojúrí fúnra ẹni. Wọ́n ní àjò kìí dùn ká gbàgbé ilé. Nígbà tó yá mo sọ padà sílẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ. Ọ̀nà igbó tí mo gbà tẹ́lẹ̀ kọ́ ni mo gbà padà o. Igbó olókìkí kan ni mo tọ̀ já. Àmọ́ gbogbo oun tí mo rí nínú igbó náà kàn ń múnmi yanu ni. Kí ló fa ìyanu? Ẹ̀yin ẹ padà wá ka apá kẹta ìtàn yìí láìpẹ́. N ó ṣàròyé ìdí abájọ, àti ìdí tí wọ́n fi ń pe igbó náà ní Igbó Funfun. Àgádágodo aláwọ̀ ìyeyè Njẹ́ ibi orí dáni sí làá gbé. Ibi orí ranni lọ làá lọ. Bẹ́ẹ̀ iṣẹ́ ori ránni làá ṣe. Èyí ló fa máalọ-máabọ̀ ojoojúmọ́ gbogbo ẹ̀dá. Iṣé òòjọ́ wọn ni wọ́n ń ṣe. Ọ̀nà àti là yìí náà ni wọ́n ń lépa. Máalọ-máabọ̀ ojoojúmọ́ yìí a máa sú ọ̀pọ̀lọpọ̀ dé’bi pé wọn kìí kíyèsí nkan lọ titi lọ́nà ibi tí wọ́n ń lọ. Kí wọ́n ṣáà tètè dé ibiṣẹ́, kí wọ́n tètè parí iṣẹ́, kí wọ́n sì tètè padà dé’lé ló jẹ wọ́n lógún. Bí i tẹ̀mi Alákọ̀wé kọ́. Ní tèmi o, mo máa ń ṣí ojú mi kalẹ̀ dáadáa ní gbogbo ìgbà ni. Mo sì máa ń ṣe àkíyèsí gbogbo oun tí ń lọ ní àyíká mi. Èmi a máa rí àwọn nkan ìyanu káàkiri gbogbo ilẹ̀ tí mò ń tẹ̀, èmi a sì máa gbé orúkọ́ Ọlọ́run ga. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, n a máa rí ẹwà nínú àwọn nkan kékèké tí àwọn míràn ò kà kún nkankan. Ṣé bó ti wu Elédùà ló ń ṣ’ọlá ẹ̀? Ọba mi a ṣèkan bí àpáta gbànyàyà, Ọba kannáà yìí a ṣe òmíràn bí ọ̀kúta wẹwẹ tí ń bẹ nínú erùpẹ̀. Èdùmàrè yìí tún ṣe iṣẹ́ ẹ̀ l’áṣepé, ó fi làákáyè jíìnkí ọmọ ẹ̀dá. Ó ní ká máa fi ọgbọ́n orí wa dárà ní ọlọ́kanòjọ̀kan. Irúfẹ́ àrà náà ni mo mà máa ń rí lọ́nà ibiṣẹ́ o. Àgádágodo aláwọ̀ ìyeyè ni nkan náà. Bíótilẹ̀jẹ́pé gbogbo èèyan tí wọ́n ń kọjá níbẹ̀ ò tilẹ̀ kíyè sí i, tàbí kí wọ́n rí i ṣùgbọ́n kí wọ́n má kà á kún nkankan. Àmọ́ èmi Alákọ̀wé, nkan arẹwà gbáà ni mo kà á kún. Tó fi jẹ́ pé mo mọ̀ńmọ̀ ya àwòrán rẹ̀ fún ayé rí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí ìmọ́lẹ̀ oòrùn tó lágbára jù, kí iyì àwọ̀ rẹ̀ lè hàn dáadáa. Ọ̀rọ̀ yìí á ti yé àwọn afẹ̀rọyàwòrán ẹgbẹ́ mi. Ẹ̀yin náà ẹ wò ó. Njẹ́ ọ̀dà tí wọ́n kun àgádágodo yìí rẹwà àbí kò rẹwà? Ẹ jẹ́ kí n gbọ́ èsì yín o. Ojúmọ́ gígùnjùlọ Àwọn àgbà Yorùbá àtijọ́ a máà sọ̀rọ̀ kan. Wọ́ ní “oòrùn ló ni ọ̀sán, òṣùpá lo ni òru”. Òótọ́ ni. Àmọ́ ìyẹn lọ́dọ̀ tíwa lọ́hùún ni o. Ẹ jẹ́ mọ̀n pé àwọn ibìkan ń bẹ tí oòrùn kò ní wọ̀ rárá lónìí? Bẹ́ẹ̀ni. Ajẹ́pé lọ́dọ̀ tiwọn níbẹ̀, àti ọ̀sán gan-gan o, àti gànjọ́ òru, ìkáwọ́ oòrùn ló wà. Ìyẹn lórí eèpẹ̀ àgbálá ayé wa yìí náà o. Ní ìlú ọba níhìín, fún wákàtí mẹ́rìndínlógún àti ìṣẹ́jú méjìdínlógójì ni oòrùn yíò ran ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kalẹ̀ yanyanyan léwa lórí kó tó wọ̀ ni nkan bí i aago mẹ́sàn-án kọjá ìṣẹ́jú mọ́kànlélógún. Aago mẹ́fà àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ni mo ya àwòrán yìí lónìí, àmọ́ ẹ wo bí oòrùn ti mún. Kódà ní ìta gbangba ńṣe ni oòrùn kanni látàrí gbọ̀ngbọ̀n. Ìdí abájọ ni pé òní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje ọdún ni ojúmọ́ gígùnjùlọ lọ́dún ní ìhà àríwá àgbáyé. Mo ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ yìí rí níbìkan. Òní tún bọ́ sí ọjọ́ Àbámẹ́ta tí í ṣe ọjọ́ ìgádùn kẹlẹlẹ. Ní tèmi Alákọ̀wé, fàájì ni mo wà o jàre. Ìrìnkèrindò Moravia Yoòbá ní àìrìnjìnnà ni kò jẹ́ ká rí abuké ọ̀kẹ́rẹ́. Ẹ wo ibi Alákọ̀wé rìn dé tó fi rí abuké erin. Ìrìnkèrindò gidi rèé o, ẹ máa bá mi kálọ. Ilẹ̀ kan ń bẹ láàrin gbùgbùn Úróòpù tí ń jẹ́ Moravia. Ilẹ̀ ọ̀hún kìkì òkè ni, ó sì kún fún àwọn igbó aginjù ńlá-ńlá àti adágún odò fífẹ̀ ní ọlọ́kanòjọ̀kan. Èmi Alákọ̀wé yín àtàtà, mo fi ẹsẹ̀ mi méjéèjì tí Elédùà fún mi rin àwọn òkè náà. Mo sọdá àwọn odò tí wọn kò jìn púpọ̀jù, mo sì rìn nínú àwọn igbó wọnnì pẹ̀lú. Ó wá ṣe bí ẹni pé èmi gan-an ni ògbójú ọdẹ nínú igbó Maravia. Ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ ibẹ̀ ni pé bíótilẹ̀jẹ́pé mo rí àwọn ẹranko kọ̀ọ̀kan t’ọ́n ṣàjèjì sí mi, n kò fojú kan ẹbọra tàbí abàmì ẹdá kankan o 🙂 . Ọpẹ́ ni fún Olódùmarè. Àmọ́ ṣá, oríṣìíríṣìí lojú rí níbẹ̀ o. Nígbàtí mo dé ẹ̀bá igbó kan, mo ṣàdédé rí nkan tó jọ agbárí ìkookò tí ẹnìkan gbé kọ́ igi. Ó dẹ́ru báni púpọ̀. Nígbà tó tún ya mo tún ń wo nkankan lókèrè tó fẹ jọ òjòlá ńlá. Ó kù díẹ̀ kí n padà lọ́nà kí n tó rí i pé okun lásán ni mo rí. Oríta mẹ́ta kan ń bẹ lọ́nà àbáwọ igbó ńlá náà. Gbogbo òkúta ilẹ̀ ibẹ̀ funfun gbòò bí iyọ̀. Àsìkò ìwọ́wé tó jẹ, àwọn ewé ti wọ́ dà sílẹ̀, wọ́n wá pọ́n kuku. Gbogbo rẹ̀ wá ń tàn winiwini nínú ìmọ́lẹ̀ oòrun. Ó wuyì púpọ̀, kódà nkan ẹwà gidi gan-an ni. Lẹ́hìn wákàtí mélòókan mo tọ igbó ọ̀hún ja sí ilẹ̀ ọ̀dàn ńlá kan tó lọ gbansasa kọjá ibi tí ojú ẹni ríran dé. Òkè kékeré kan ń bẹ láàrin ilẹ̀ ọ̀dàn náà. Ní orí òkè náà ni mo ti rí nkan ìyàlẹ́nu. Ilé gogoro kan mà ni o. Ilé ọ̀hún ga tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, n kò lè fojú rí òkè rẹ̀ láti ìsàlẹ̀. Ó tún wá ṣe ṣoṣoro lókè, ó dàbí ẹni pé ó fẹ́ gún ojú-ọ̀run lábẹ́rẹ́. Àwọn kan ti wí fún mi tẹ́lẹ̀ náà pé àràmàndà ni ilé ọ̀hún jẹ́. Àmọ́ tí wọ́n bá wípé “Ìròhìn ò tó àmójúbà” bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ yìí rí. Kíákíá ni mo bá tẹsẹ̀ mọ́n’rìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í tọ ilé náà lọ. Nígbà tí mo súnmọ́ ọ̀n díẹ̀ sí i, mo ṣàkíyèsí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan èjèèjì tí àwọn náà ń tọ ilé gogoro náà lọ. Ní òjijì ni gbogbo wọn bá dúró, wọ́n gbójú sókè. Èmi náà bá wòkè pé kí wa ló dé? Ẹ̀rù Ọlọ́run sì bà mí. Òjò ti ṣú dẹdẹ lójijì. Àwọn ìkúùkù-òjò sì ti bo bí ìdajì ilé náà lókè. Àrá sán kàáwòóóó! Òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Gbogbo wa bá bẹ́ sí eré sísá. A súré tete tọ ilé ọ̀hún lọ pé bóyá a lè rí ibìkan gọ sí kí gbogbo aṣọ wa má baà tutù tán. Ṣùgbọ́n oun tó dẹ́rù Ọlọ́run bani lọ́jọ́ náà ni pé bí òjò ṣe ń rọ̀ lemọ́-lemọ́ lé wa lórí, bẹ́ẹ̀ oòrùn ń ràn kalẹ̀ níhà ibòmíràn, tí a sì ń wò ó lọ́ọ̀ọ́kán. Òṣùmàrè wá fà kàlákìní lójú ọ̀run. Ah! Ẹ̀yin èèyàn mi nkan ńbẹ o! Nígbà tó yá a kúkú dé iwájú ilé gígá roro náà. Ẹ bi mí pé kíni ojú mi rí níbẹ̀ ẹ̀yin èèyàn mi? Gbogbo rẹ̀ ni n ó rò fún yín ní apá kèjì ìtàn yìí. Ẹ padà wá láìpẹ́. Ẹ yíò ka bambarì ìtàn. Ẹ kú ojú lọ́nà o Àwọn Omi Sulis Ẹni tó wípé Alákọ̀wé ìwọ dà láti’jọ́ yìí? Ó mà ṣe fírífírí kẹ̀. Enítọ̀hún ṣeun aájò wa jàre. Àṣá ò pẹ́ lóko bẹ́ẹ̀ rí ọ̀nà ló pọ̀ Ìrìnàjò mà ni Alákọ̀wé tẹsẹ̀ bọ̀ ní ọlọ́kanòjọ̀kan o. Mo dé ìhà ìlà-oòrùn àgbáyé níbi tí ọjọ́ ti ń kọ́kọ́ mọ́n. Mo dé ìwọ̀-oòrùn níbi tí agbami òkun ti lọ kánrin-kése kọ́já ibi ojú rí. Àní mo dé àríwá ayé níbi yìnyín gbé rọ̀ dàálẹ̀ bí òjò. Gúsù ńkọ́? Níbi oòrùn ti ń yọ lóru gànjọ́, gbogbo rẹ̀ ló sojú èmi kinní yìí. Ìlé-ayé yìí kún fún nkan àdìtú àti ìyanu. Ìrìn gbé mi dé ìlú kan tí ń jẹ́ Bath. Orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ni ìlú náà wà. Nkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún ṣẹ́hìn ni wọ́n tẹ ìlú náà dó sí etí odò Avon. Àwọn ará Róòmù tí wọ́n tẹ̀ ẹ́ dó sọ ọ́ lórúkọ ‘Aquae Sulis’ (Àwọn Omi Sulis). Òrìṣà ayé-àtijọ́ kan nílẹ̀ yìí ni ó ń jẹ́ Sulis. Àwọn ọmọ onílẹ̀ tí wọ́n wà níbẹ̀ kí àwọn Gẹ̀ẹ́sì tó dé ni wọ́n ń bọ òrìṣà náà nígbà náà. Ìdí tí wọ́n ṣe sọ ọ́ ní Aquae Sulis ni pé sẹ́lẹ̀ru omi gbígbóná kan wà níbẹ̀ tí wọ́n gbàgbọ́ pé a máa wo aláìsàn sàn, a sì máa múni lára dá. Nítorí náà àwọn ará Róòmù kọ́ ilé-ìwẹ̀ ńlá kàbìtì yí àwọn sẹ́lẹ̀ru náà po. Ìlé ọ̀hún wá dúró gẹ́gẹ́ bí ilé ìwòsàn àti ìgbafẹ́ ọlọ́kanòjọ̀kan fún àwọn arawọn, àti àwọn ọmọ onílẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́lá. Lẹ́hìn ìgbà díẹ̀, òkìkí Aquae Sulis kàn káàkiri gbogbo ìlẹ̀ Róòmù ìgbà náà. Ṣé ìjọba amúnisìn ni Róòmù jẹ́ nígbà náà, a jẹ́ pé títí dé ilẹ̀ Ígíbíìtì àti India ni òkìkí rẹ̀ kàn dé. Àsìkò yìí ni ìgbà tí Jésù wà ní ilé-ayé. Nígbà náà kò sí ibi aláìsàn ò kí ń wá ìwòsàn dé. Káàkàkiiri àgbáyé ni àwọn ènìyàn ti rin ìrìnkèrindò dé Aquae Sulis pé kí àwọn lè rí ìwòsàn. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ láyé-àtijọ́ tún fún àwọn èèyàn ìgbà náà ní ìdánilójú pé agbára Sulis ń bẹ nínú omi náà. Olorì Gẹ̀ẹ́sì kan tí kò rí ọmọ bí lọ síbẹ̀, ó sì wẹ̀ nínú omi Sulis. Ló bá di igi ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí í gb’ódò tí Yoòbá ní kìí y’àgàn. Wẹ́rẹ́, olorì finú ṣoyún, ó sọ̀ láyọ̀. Nígbà tó yá ni ìlú ọ̀hún gbòòrò dé bó ti rí. Ìjọba Róòmù kásẹ̀ nílẹ̀ káàkiiri àyé, àwọn Gẹ̀ẹ́sì gba àkóso ìlú náà, wọ́n sì yí i lórúkọ padà sí Bath.  Lóde òní, Bath jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú pàtàkì ní orílẹ̀ UK. Ẹní bá ṣe àbẹ̀wò dé UK, kí enítọ̀hún yáa gbìyàjú dé ìlú Bath. Ẹ ó ríran wò! Wọ́n ní tí ẹ bá dé ibi sẹ́lẹ̀ru Sulis, tí ẹ ju owó sínú ẹ̀, ẹ di olóríire nìyẹn.  Èyí ló ká ẹlòmíràn lára tó fi ju odidi pọ́ùn kan sínú omi.  Ṣé mákọjá mi Olùgbàlà kìí ṣe orin àkúnlẹ̀kọ àbí? Òun ló dífá fún Alákọ̀wé ní ìlú Bath, tó ju pọ́ùn méjì sínú omi.  Àpèmọ́nraẹni là á pe tèmídire 🙂 Omi A kìí bómi ṣọ̀tá – ó ṣèwọ̀. Ṣé omi làbùwẹ̀, òun làbùmu.   Jíjí tí mo jí ní kùtù-kùtù, omi ni mo fi bọ́jú, òun ni mo fi fọnu.   Mo tọ orílẹ̀ yìí dé ìpẹ̀kun àríwá mo kan agbami òkun àwòyó ni ń bẹ ní gúsù.   Njẹ́ orí rẹ làá tí tu'pọ́n inú rẹ ni tọmọdé tàgbà ti ń játùbú.   Kòṣémánìí ni ọ́ omi Ìwọ gan-an ni kòríkòsùn àrin òru   Orí rẹ ni Olódùmarè tẹ́ ilé-ayé lé Ẹni fojú di ọ́, olúwarẹ̀ kàbùkù.   Ṣé ìwọ lọ̀ ń bẹ nínú ìtọ̀, ìwọ lọ̀ ń bẹ nínú itọ́ ìwọ ni omijé ti inú ẹyinjú   Orí mi má mà jẹ́ n pàdánù omi Kòsí oun tí ń gbani lọ́wọ́ omi àfi ikú.   Fìlà wo? Yoòbá ní a rí ẹni tó lórí tí kò ní fìlà, a r’ẹ́ni tó ní fìlà tí kò lórí. Lọ́lá Ọlọ́run Ọba, a r’ẹ́ni tó lórí kẹ̀dẹ̀rẹ̀-kẹdẹrẹ, tó tún kó fìlà jọ bí ilẹ̀ bí ẹní. Irúfẹ́ enítọ̀hún ni Alákọ̀wé yín. Bẹ́ẹ̀ni, Olúwa ló fi fún mi kìí ṣe ènìyàn. Ṣùgbọ́n ẹ gbọ́ o, ṣèbí bí a ó ba wọ fìlà, dandan ni kó bá aṣọ mu. Àfi tí ènìyàn bá fẹ́ fi’rarẹ̀ wọ́lẹ̀ ní àwùjọ. Ṣé ẹ mọ̀n tẹ́lẹ̀ pé ará oko ni èmi jẹ́. Èmi ò mọn kíni fáàrí tí ń lọ lóde. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ará èkó ti máa ń wí fún mi -“o ò damọ̀”. 🙂 Toò. Yoòbá bọ̀ wọ́n ní “Ajá ìwòyí là ń lé sí ehoro ìwòyí”. Ajẹ́pé ẹ̀yin olólùfẹ́ alákọ̀wé.com àti òntẹ̀lé ni màá bẹ̀ sọ́rọ̀ yí o. Ẹ dákun fìlà wo ló ba aṣọ yìí mu jùlọ? Ati pé èwo níbẹ̀ lo wuyì jù? Ẹ yáa tètè fún mi l’ésì o, nítorí òde tí mò ń lọ náà, àrin àwọn onífáàrí gidi ni. Iṣẹ́ ló ń ṣíwájú ìgbádùn Wọ́n ní ẹni tó da omi sí’wájú, ẹnítọ̀hún yó tẹ ilẹ̀ tútù. Ìyẹn ni pé kí a tó jẹ ìgbádùn, iṣẹ́ ní í ṣíwájú ẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí ló díá f’Álákọ̀wé lọ́jọ́ òní. Njẹ́ ẹni tó fẹ́ jẹ ọbẹ̀ ilá yíò kọ́kọ́ rẹ́’lá. Àbí ẹni tó fẹ jẹ àmàlà, kí ìgùnwọ́ olúwarẹ̀ yáa gbáradì nítorí ọmọrogùn àti ìkòkò ọkà wọn kìí ṣ’ọ̀rẹ́ arawọn. Àmọ́ o, ẹni tó bá tẹra mọ́n’ṣẹ́, ó di dandan kó jẹ̀rè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Bótiwù kó roni lójú láti rẹ́ ilá, tàbí láti ro àmàlà, tí oúnjẹ bá dé’lẹ̀ tán ìgbádùn dé! Ẹkú ìsinmi òní o. Ẹ bá mi’re 🙂 Àdìtú Stonehenge Ní ìyálẹ̀ta ọjọ́ òní ni àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ilẹ̀ yìí ti jí dé ibi àkójọpọ̀ okúta ayérayé nì tí wọ́n ń pè ní Stonehenge. Ìdí abájọ ni pé lọ́jọ́ òní, tí í ṣe ọjọ́dọ́gba, ni ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé. Ìyẹn ni pé ìgbà ọ̀gìnìntìn ti ré kọjá, a ti bọ́ sí ìgbà ọ̀tun. Ní ayé àtijọ́ kí ẹ̀sin Kìrìstẹ́nì tó dé’lẹ̀ yìí, àwọn náà ní ẹ̀sìn ìbílẹ̀ tiwọn. Ọ̀kan nínú àwọn àjọ̀dún tó rọ̀ mọ́n ẹ̀sìn náà ni àjọ̀dún òrìṣà Eostre. Eostre ni òrìṣà nkan tuntun, ìgbà tuntun, bí ọmọ bíbí. Ìdí èyí ni a fi rí orúkọ abo òrìṣà yìí nínu “E(o)strogen” fún àpẹrẹ. Ẹ ka nkan tí mo kọ nípa Eostre àti Easter Stonehenge ti pẹ́ ní orílẹ̀ yìí tó jẹ́ pé a kò lè sọ pàtó pé àwọn báyìí ni wọ́n kọ́ ọ síbẹ̀. Orísìíríṣìí ìtàn atẹnudẹ́nu ló dárúkọ rẹ̀, àmọ́ kòsí ẹni tó mọn òdodo ọ̀rọ̀. Bótiwù kó jẹ́, nkan ìyanu gidi ni òkuta yìí. Lọ́jọ́ òní, àti lọ́jọ́dọ́gba ìgbà ìwọ́wé, ìlànà tí oòrùn tọ̀ láti ilà dé ìwọ̀ lókè ọ̀run bá ti Stonehenge mu rẹ́gí-rẹ́gí nílẹ̀. Èyí fi hàn wá pé làákáyè ńlá ni àwọn tí wọ́n kọ́ ọ ní. Àti pé wọ́n ní ìmọ̀jinlẹ̀ gan-an ni nípa ojú ọ̀run. Àwọn òkúta ọ̀hún tóbi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, nkan àdìtú ni bi wọ́n ṣe gbé wọn dé ibi tí wọ́n wà láàrin ọ̀dàn – tí kò sí àpata kankan ní ìtòsí. Ó ṣe èmi Alákọ̀wé gan-an ní kàyéfì ní ìgbá tí mo f’ojú mi kòró-kòró kàn án. N kò rí nkankan sọ, àfi pé Ọlọ́run tóbi l’ọ́ba. Ẹ darapọ̀ mọ́n wa lórí Twitter lónìí fún ìgbélárugẹ èdè Yorùbá. Eré Òṣùpá Kọfí ab'òdòdó lórí Àṣà kan wà ní’lẹ̀ yìí tó jọ mí lójú. Àṣà ọ̀hún ni bí wọ́n ṣe máa ń dárà sí oúnjẹ àti oúnmu wọn. Pàápàá ní àwọn ilé-oújẹ, gbogbo nkan tí ń bẹ níbẹ̀ á wá máa ṣe kánmi-kànmì-kánmi, á wọ̀nni lójú gbáà. Tí olúwarẹ̀ ò bá ṣọ́ra, èèyàn á kó gbogbo owó ọwọ́ ẹni fún wọn níbẹ̀. Ẹ̀yin ẹ wo àwòrán kọfí tí mo yà ní ìjẹta. Ẹ wo bí wọ́n ṣe dárà sí i lórí bí ẹni pé ọba kan ló fẹ́ mu ú. Ìkẹ́ àti ìgẹ̀ gidi ni wọ́n fi pò ó fún mi. Òun ni mo fi yà á l’áwòrán kí n tó mu ú o jàre. Kódà nígbà ti mo mu ú tán, wéré ni mo tún rà’míì mu. Otútù ń bẹ níta n kò sì re’bìkan 🙂 Kọfí ab’òdòdó lórí Àṣà kan wà ní'lẹ̀ yìí tó jọ mí lójú. Àṣà ọ̀hún ni bí wọ́n ṣe máa ń dárà sí oúnjẹ àti oúnmu wọn. Pàápàá ní àwọn ilé-oújẹ, gbogbo nkan tí ń bẹ níbẹ̀ á wá máa ṣe kánmi-kànmì-kánmi, á wọ̀nni lójú gbáà. Tí olúwarẹ̀ ò bá ṣọ́ra, èèyàn á kó gbogbo owó ọwọ́ ẹni fún wọn níbẹ̀. Ẹ̀yin ẹ wo àwòrán kọfí tí mo yà ní ìjẹta. Ẹ wo bí wọ́n ṣe dárà sí i lórí bí ẹni pé ọba kan ló fẹ́ mu ú. Ìkẹ́ àti ìgẹ̀ gidi ni wọ́n fi pò ó fún mi. Òun ni mo fi yà á l'áwòrán kí n tó mu ú o jàre. Kódà nígbà ti mo mu ú tán, wéré ni mo tún rà'míì mu. Otútù ń bẹ níta n kò sì re'bìkan 🙂   Ẹ kú àṣekù ọdún o Ẹ nlẹ́ o ẹ̀yin èèyàn mi. Báwo lẹ ṣe wọnú ọdún titun? Pẹ̀lú ìdúpẹ́ àti àdúrà àbí? Mo jẹ́rìí yín lọ́pọ̀lọpọ̀. Kòní bàjẹ́ láíláí. Àṣẹ Èdùmàrè. Ire ọdún titun á kárí gbogbo wa o. Àmín Olúwa. Toò, gẹ́gẹ́ bí ìṣe mi Alákọ̀wé yín tòótọ́, àwọn àwòrán tó jọjú ni mo mú wá lónìí o. Ẹ gbà'wọ̀nyí ẹ fi bẹ̀rẹ̀ ọdún titun. Ẹ̀yin tí ẹ wo àwọn àwòrán wọ̀nyí, ojú yín ò ní fọ́. Kọ̀mpútà yín ò ní gbiná nígbà kankan. Lọ́lá Ọbalókè. Èmi náà nkọ́? Ìka mi ò ní dá, kò ní ṣẹ́, kò ní gé. Ẹ̀rọ ayàwòrán mi ò ní paṣẹ́tì o. Àṣẹ Elédùà. Ọdún tuntun wọlé Yorùbá bọ̀ ó ni “…ogún ọdún ń bọ̀ wá d’ọ̀la”.  Ọjọ́ wo náà la bẹ̀rẹ̀ 2013 ná tó ti yáa tún káṣẹ̀ńlẹ̀ báyìí? Ab’ẹ́ẹ̀rí nkan? A jẹ́ pé àsìkò kò dúró de ẹnìkan.  Ayé ń yí lọ biribiri bí òkúta, àwa ẹ̀dá ń tọ̀ ọ́.  Ọdún tuntun tó wọlé dé yìí, á mú’re tọ̀wá wá.  Ọdún á yabo fún gbogbo wa o.  Mo kí gbogbo yín kú àlàjá 2013.  Ẹ sì kú ọdún tuntun 2014! Ire o! Ẹkú ọdún ẹkú ìyèdún Ìmọ́lẹ̀ l'ọkọ òkùnkùn Ìjẹta, mọ́júmọ́ àná, ni ọjọ kọkàlélógún sí ìkejìlélógún oṣù kejìlá ọdún. Alẹ́ yìí ni alẹ́ gígùnjùlọ lọ́dún. Fún wákàtí mẹ́rìndílógún gbáko ni òkùnkùn ṣú biribiri, ìyẹn ní Ígíláàndì ní’hàhín. Ní’hà ibòmíì, ilẹ̀ ṣú fún wákàtí mọ́kànlélógún. Kódà, a rí ibi tí ilẹ̀ ò tilẹ̀ mọ́n rárá lọ́jọ́ náà. N kò fi parọ́ rárá. Ọpẹ́lọpẹ́ iná tí kìí lọ, tí kìí dákú ní’lẹ̀ yìí. Gbogbo ojú títì a tanná niniini. Láàrin òru gan-an, gbogbo ilé ní ìgboro ìlú a tanná kalẹ̀ gbòò. Gbogbo ẹ̀ á wá mọ́nlẹ̀ dáadáa. Pàápàá jùlọ, àsìkò tí a ti súnmọ́ àjọ̀dún kérésìmesì gbọ̀ngbọ̀n, oríṣìíríṣìí iná aláràbarà ni àwọn ará ilẹ̀ yìí fi ń ṣe ìgboro wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Yirinyirin aláràbarà ọlọ́kanòjọ̀kan ni èèyàn a máa rí níbikíbi tí èèyàn bá lọ. Ó wuyì gbáà. Ìmọ́lẹ̀ l’ọkọ òkùnkùn Ìjẹta, mọ́júmọ́ àná, ni ọjọ kọkàlélógún sí ìkejìlélógún oṣù kejìlá ọdún. Alẹ́ yìí ni alẹ́ gígùnjùlọ lọ́dún. Fún wákàtí mẹ́rìndílógún gbáko ni òkùnkùn ṣú biribiri, ìyẹn ní Ígíláàndì ní'hàhín. Ní'hà ibòmíì, ilẹ̀ ṣú fún wákàtí mọ́kànlélógún. Kódà, a rí ibi tí ilẹ̀ ò tilẹ̀ mọ́n rárá lọ́jọ́ náà. N kò fi parọ́ rárá. Ọpẹ́lọpẹ́ iná tí kìí lọ, tí kìí dákú ní'lẹ̀ yìí. Gbogbo ojú títì a tanná niniini. Láàrin òru gan-an, gbogbo ilé ní ìgboro ìlú a tanná kalẹ̀ gbòò. Gbogbo ẹ̀ á wá mọ́nlẹ̀ dáadáa. Pàápàá jùlọ, àsìkò tí a ti súnmọ́ àjọ̀dún kérésìmesì gbọ̀ngbọ̀n, oríṣìíríṣìí iná aláràbarà ni àwọn ará ilẹ̀ yìí fi ń ṣe ìgboro wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Yirinyirin aláràbarà ọlọ́kanòjọ̀kan ni èèyàn a máa rí níbikíbi tí èèyàn bá lọ. Ó wuyì gbáà. Mandela oníwà pẹ̀lẹ́ wàjà Ikú bàjẹ́. Nígbà míì a fi ẹni ibi sílẹ̀, a mú ẹni ire lọ. Àmọ́ lẹ́yìnọ̀rẹyìn o, kòsí ẹni tí kò ní kú, ti oko baba rẹ̀ ní di ìgbòòrò – gẹ́gẹ́ bí òwe Yoòbá kan – a dífá fún Rolihlahla tó w'àjà l'ọ́sẹ̀ tó kọjá, ti gbogbo aráyé ń ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. Ẹni ire gbáà ni ikú mún lọ l'ọ́tẹ̀ yìí o. Báwo la ṣe lè ṣe àpèjúwèé olóògbé Mandela ná? Tí a bá pè é ní Ìlúmọ̀míka, bí ẹní tẹ́mbẹ́lú rẹ̀ ni. À bá pè é ní Gbajúmọ̀, bí kìí ṣe bí ẹní dá a kéré ni. Kò kúkú l'áàńṣàpèjúwèé kankan ẹ̀yin èèyàn mi. Òdú ni bàbá yìí, kìí ṣe ẹni tí olóko kò mọ̀n. Ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ ni alàgbà yìí nígbà ayé rẹ̀, kìí ṣ'àmọ̀ fún olódò. Iṣẹ́ ribibi lọ́ ṣe fún ànfàní àwa adúláwọ̀ káárí ayé tí kò ṣé fi ẹnu sọ tán. A kò lè gbàgbé rẹ láíláí Mandela. Pàápàá n ó máa ṣe ìrántí ọjọ́ tí mo rí ọ lójúkorojú ní Orílẹ̀ Senegal láìpẹ́ tí wọ́n tú ọ sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n. Èmi àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí a wá pàdé rẹ lọ́jọ́ náà. Àwọn tí o fún ní ìmísí kò l'ónkà. Ọ̀la ni wọ́n máa sin olóògbé àgbàlagbà aṣíwájú yìí. Kí Ọlọ́run dẹ'lẹ̀ fún ẹni ire. Ajẹ́pé ó di gbére, ó di àrìnàkò, ó di ojú àlá. Má jẹ ọ̀kùn, má jẹ ekòló, oun tí wọ́n bá ń jẹ ní àjùlé ọ̀run ni kí o máa bá wọn jẹ. Kò séni tí kò ní jẹ́ ìpe Olódùmarè. Ọ̀run nìkan ni àrèmabọ̀. Tata Madiba Rolihlahla Mandela. Sùn're o! Láìsí ìmọ́lẹ̀ kòsí àwòrán Àsìkò òtútù ti wọlé dé tán, ilẹ̀ sì ti ń tètè ṣú lọ́dọ̀ wa níbí. Nígbà míì gan-an, tí òjò bá ṣú dẹdẹ láti òwúrọ̀ dé ìrọ̀lẹ́, á máa dàbí ẹni pé ilẹ̀ ò mọ́n rárá lọ́jọ́ náà ni. Ìdí ẹ̀ lèyí tó fi jẹ́ pé ọjọ́ tí oòrùn bá yọ, tí ojú-ọjọ́ bá fẹ́ ṣe bí ẹní mọ́n díẹ̀, kíà-kíà ni gbogbo wa má jáde síta láti gbádùn ìmọ́lẹ̀ àti lílọ́wọ́rọ́ oòrùn. Pàápàá àwa ayàwòrán, inú wa a máa dùn tí a bá ti rí irú ọjọ́ báyìí. Ńṣe la máa sáré bọ́ síta pẹ̀lú ẹ̀rọ ayàwòrán wa àti àwọn irinṣẹ́ rẹ̀. Nkankan tó máa ń wuni púpọ̀ láti yà láwòrán ní àsìkò ìkórè tí a wà yìí ni àwọn ewéko àti àwọn igi. Àwọ̀ àwọn ewéko a máa jọ́ni lójú púpọ̀. Púpọ̀ nínú àwọn igi ni gbogbo ewé wọn ti rẹ̀ dà sílẹ̀ tán pátápátá. Àwọn igi míì tí wọ́n bá ti gbẹ á wọ́ lulẹ̀ tí ìjì kan bá jà, tàbí tí atẹ́gùn òjò tí ó lágbára bá fẹ́ lù wọ́n. Díẹ̀ nínú àwọn àwòrán tí mo yà ní àárọ̀ yìí ni ìwọ̀nyí. Igi ńlá ni igi ọ̀pẹ Ìrìnàjò kan tí mo rìn dé Andalusia ní orílẹ̀èdè Spain níjọ́sí, oríṣìí nǹkan l’ojú rí níbẹ̀.  Mo rí awọn ìlú kan tí ó jẹ́ pé òkúta funfun gbòò ni wọ́n fi kọ́ gbogbo àwọn ilé ibẹ̀.  Mo rí afárá ńlá alájà méfà.  Kódà mo tún rí ibi tí àwọn odidi igi ti ń hù lábẹ́ odò.  Sùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan ìyanu tí mo rí, èyí tó pe àkíyèsí mi jùlọ ni bí igi ọ̀pẹ ṣe pọ̀ níbẹ̀ tó.  Kò sí ibi tí igi ọ̀pẹ ò hù sí káàkiri.  Ní àsìkò tí mo lọ tún wá bọ́ sí ìgbà ìkórè.  Ajẹ́pé àwọn ẹyìn ti pọ́n, tí wọ́n sì rẹ̀ dà sílẹ̀ káàkiri.   Kí ló wá yà mí lẹ́nu?  Ẹ jẹ́ mọ̀n pé ibi àwọn ẹyìn bá rẹ̀ sí, ibẹ̀ náà ni wọ́ ń rà sí o!  Àyàfi tí ẹyẹ tàbí ọ̀kẹ́rẹ́ bá fi jẹ.  Láàrin ìgboro kẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba a máa fi ọkọ̀ akólẹ̀ kó wọn lọ dà sí ààtàn.  Wọn kò ka igi yìí kún nǹkanan níbẹ̀.  Èso igi náà kò jọ wọ́n lójú pẹ̀lú. Ní ilẹ̀ Oòduà, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe káàkiri àwọn ilẹ̀ adúláwọ̀ gbogbo, pàtàkì ni igi ọ̀pẹ jẹ́.  Ara igi yìí la ti ń rí ẹmu funfun tí ��e ògùrò tí àwọn àgbà ò jẹ́ fi ṣàwàdà.  Ara rẹ̀ la ti ń rí epo pupa tí í ṣe agbátẹrù iṣu lọ́nàfun. Ara rẹ̀ la ti rí màrìwò tí a fi ń ṣe ọwọ̀ ìgbálẹ̀ at ọjọ̀ ewédú. Èkùrọ́ ńkọ́?  Òun ló ń fún wa ní àdí èkùọ́ àti òrí.  Àwọn kan a tún máa fi màrìwò ṣe òrùlé ilé.  Bẹ́ẹ̀ wọn a máa fi èpo ẹyìn gbígbẹ ko iná ààrò kó lè baà jò dáadáa.  Àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ìdí rèé tó fi yà mí lẹ́nu pé igi pàtàkì yìí kò da nǹkankan lóju wọn, tí èso rẹ̀ sì ń ṣòfò dànù bẹ́ẹ̀.  Ǹjẹ́ ẹ jẹ́rìí Alákọ̀wé yín bí?  Gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọ Oòduà, mo wá ibìkan tó tẹjú pẹrẹsẹ, mo wá òkúta kan, mo ṣa èkùọ́ mélòókan, mo pa wọ́n, mo dà wọ́n sẹ́nu, mo jẹnu wọ̀mù-wọ̀mù, mo gbé e mì kàló.  Gbogbo wọn wá ń wò mí bàùn bí àguntàn Ìbàdàn.  Èmi náà bá ranjú mọ́n wọn padà.  Mo jẹ́ kó yé wọn pé “òkò tí a bá sọ lu ọ̀pẹ ní í sọ padà sí ẹni”.  Òwe Yoòbá kan ni. Àgbò Iléyá Orí yéye ní mògún, t’àìṣẹ̀ ló pọ̀. A díá fún àgbò tó di ẹran Iléyá. Ẹ gbọ́ o. Ọ̀ràn kí ni àgbò dá tó fi jẹ́ pé ọdọọdún ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún mùsùlùmí ń yọ ọ̀bẹ́ sí i lọ́rùn? Láyé àtijọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ọkùnrin kan ń bẹ nígbà náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ibrahim. Ọmọ ọkùnrin kan ṣoṣo ni arákùnrin náà bí. Ó sì pẹ́ kí ó tó ríi bí. Ibrahim jẹ́ ẹnìkan tó ní ìfẹ́ àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run gidi gaan ni. Ó wí pé kòsí nkan náà tí Ọlọ́run fẹ́ tí òun kò ní ṣe. Ọjọ́ kan dé tí Olódùmarè dán Ibrahim wò. Ó wí fún un pé kó fi àrẹ̀mọ rẹ̀ rúbọ sí Òun. Ìyẹn Ishmael, tí í ṣe ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo. Láìsí àní-àní kankan, Ibrahim pe Ishmael kó nìṣó. Ishmael náà ní ìtẹríba fún Ọlọ́run àti fún bàbá rẹ̀. Òun náà kò ṣiyè méjì, ó gbéra ó tẹ̀lé bàbá rẹ̀. Nígbà tí Ibrahim ṣetán láti pa ọmọ rẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ, tó gbọ́wọ́ idà sókè ni Ọlọ́run fi ọmọ àgùntàn ránṣẹ́ láti fi rọ́pò ọmọ ènìà. Ènìyàn pàtàkì gbáà ni Ibrahim jẹ́ lórí orílẹ̀ ayé yìí. Ànábì Ọlọ́run ni àwọn ẹlẹ́sìn Islam kàá kún. Ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni ó jẹ́ fún àwọn Kìrìstẹ́nì àti àwọn Júù (Yawúdí) pẹ̀lú. Kódà, ọmọ Ibrahim tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Isaac ni babańlá àwọn ẹ̀yà Isreal àti Juda. Àríyànjiyàn kan nbẹ nínú ìyàtọ̀ tó wà nínú ìtàn yìí. Àwọn Kìrìstẹ́nì àti Júù wí pé ọmọ Ibrahim kejì Isaac ni Ọlọ́run ní kó fi rúbọ sí Òun. Ìdí ẹ̀ rèé tó fi jẹ́ pé àwọn mùsùlùmí a máa pa ẹran àgbò ní àjọ̀dún yìí tí orúkọ rẹ̀ ń ṣe Eid al-Adha ní èdè Lárúbáwá. Ìléyá ni wọ́n ń pè é ní èdè Yorùbá nítorí pé nígbàtí àgùntàn ti rọ́pò ènìà lójúbọ, Ibrahim wí fún Ishmael pé iléyá! Ọ̀pá tírín kanlẹ̀ ó kan ọ̀run. Kíni o? A ti wá bọ́ sí ìgbà òjò wàyí o. Ojoojúmọ́ ni òjò ń rọ̀ báyìí. Ẹni tí kò bá wọ'ṣọ òjò, òtútù ni olúwarẹ̀ ń fi ṣeré. Àmọ́ ó kúkú ti mọ́n wọn lára ní ilẹ̀ yí. Òjò ò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa rọ̀ báyìí. Àbáláyé ni. Olúkálukú ti mú àbùadà rẹ̀ lọ́wọ́ lọ ibiṣẹ́. Gbàrà tí òjò ba bẹ̀rẹ̀ ni olúkálukú ń nà án sókè borí. Ìbùkún ni òjò jẹ́ o jàre. Máa rọ̀ lọ́. Ìmísí ayọ̀ Yoòbá ní “Kùtù-kùtù kìí jóni lẹ́sẹ̀ bí ọ̀sán”. Torí ìdí èyí, èmi a máa tètè jí ṣe oun tí mo ní ṣe lóòjọ́. Pàápàá nígbà ooru tí oòrùn máa ń tètè là ní ìlú yìí. Ojúmọ́ a ti sáré mọ́n ní nkan bí ago mẹ́fà òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n a ti kọjá ọjọ́dọ́gba tó síwájú ìgbà-ìwọ́wé (ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ rèé). Ajẹ́pé àwọn ewé ti bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́ lórí àwọn igi. Àpẹrẹ pé àwọn igi wọ̀nyí àti àwọn ewéko gbogbo ti ń gbáradì fún ọ̀gìnìntìn tó ń bọ̀ lọ́nà. Ìgbà yìí a máa rẹwà púpọ̀. Àwọn ewéko a máa pa àwọ̀ dà, ewé wọn a máa pọ́n kuku, wọ́n a rí kàlákìnní. Ṣùgbọ́n bótiwù kí òde rẹwà tó, àsìkò yí ni àmì ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn máa ń ṣábàá bẹ̀rẹ̀ sí í farahàn lára àwọn ènìà. Àwọn onímọ̀jìnlẹ̀ ni wọ́n mọn ìdí abájọ, àmọ́ àyípadà sí ètò ìlà àti ìwọ̀ oòrùn kópa nínú ìmúrẹ̀wẹ̀sìbáni yìí. Síbẹ̀-síbẹ̀, àwọn nkankan a máa mú inú ẹni dùn. Fún àpẹrẹ, mo rí àwọn òdòdó kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ta, bótilẹ̀jẹ́pé ìgbà ìwọ́wé ni a wà yí. Mo tún rí àwọn ewé kọ̀ọ̀kan tí àwọ̀ wọ́n tanná niniini, bótilẹ̀ṣepé àwọn ewé ìyókù ti ń panná. Eyí a máa fúnni ní ìmísí ayọ̀, a sì máa lé ìrẹ̀wẹ̀sì sí kọ̀ọ̀rọ̀. Mo kí gbogbo ẹni tó fi ìhà aríwá àgbáyé ṣe ibùgbé kú ìpalẹ̀mọ́ ọ̀gìnìntìn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ dé o. Àjọ̀dún #YAF Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ìyẹn Àbámẹ́ta àti Àìkú ọjọ́ 27 àti 28 oṣù yí, gọngọ sọ ní agbègbè Hackney. Ayẹyẹ àṣà ọnà Yorùbá ló ṣẹlẹ̀ ní ọgbà Clissold fún ọjọ́ méjì gbáko. Ọdún kẹẹ̀rin tí àjọ̀dún náà ṣẹlẹ̀ rèé. Wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ fún àjọyọ̀ gbogbo ọmọ káàárọ̀-oòjíire ni, àti àwọn ti ibi tí àṣà wa tàn dé káàkiri àgbáyé bíi Brasil àti Kuba. Ọrísìírírìí ni wọ́n ṣe létò, àmọ́ èyí tó pabambarì ni Batala tí í ṣe ẹgbẹ́ onílù. Orílẹ̀èdè Ígílándì ni wọ́n ti wá àmọ́ irúfẹ́ ìlù tí wọ́n lù, Brasil ni àṣà ọ̀hún ti jẹyọ. N kò bá kọ jù báyìí lọ, àmọ́ kíní ọ̀hún ò tiẹ̀ wúni lórí lọ títí o jàre. Àwọn olóòtú ètò gbìyàjú pé kí ayẹyẹ ọ̀hún ó l'árinrin, àmọ́ àwọn èèyàn wa ò kọbiara sí i. Bótilẹ̀jẹ́pé àwọn èèyàn wa tí wọ́n fi ìlú Lọndọn ṣe ibùgbé pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní, pàápàá ní agbègbè Hackney gan-an, àwọn ọmọ Yoòbá tó yọjú síbẹ̀ lè má ju mẹ́wàá lọ. Ṣé ẹ mọ̀ pé nkan tiwa ò kí ń jọ wá lójú lọ lo títí. Kání òṣèré Amẹ́ríkà kan ló yọjú sí agbègbè náà báun, ọgbà náà ò bá kún dẹ́mú-dẹ́mú ni. Kí Edùmàrè ko wa yọ. Nkan kejì tó kù díẹ̀ káàtó ni pé àwọn àwo orin tí wọ́n lù, àsán azonto ni. Èmi ò fi etí mi gbọ́ orin Yoòbá ẹyọkan ṣoṣo níbẹ̀ o. Kí ló dé? Yoòbá ni ọba ìlù, àwa ni ọba gbogbo orin. Ìgbà tó ṣe díẹ̀ ni òjò bá bẹ̀rẹ̀, tí àrá ń sán fààràrà. Èmi lérò pé bóyá Olúkòso ń bínú ni. Àrẹ̀mú ò gbọ́ ìlù bàtá kankan, ló bá rọ̀jò lé kiní ọ̀hún jàre. Ni olúkálukú wá sá bọ́ sábẹ́ àwọn ìsọ̀ olónjẹ. Mo jẹ súyà. Mo jẹ àsáró. Mo tún fi omi tútù lé e. Mo rìn káàkiri àwọn ìsọ̀ aláṣọ kọ̀ọ̀kan. Ìgbà tó yá tó dàbí ẹni pé wọn fẹ́ fi azonto di olúwarẹ̀ létí, ni mo bá kọrí'lé ní tèmi o jàre. Ìyókù tún di ọdún tí ń bọ̀, kí Ẹlẹ́mìí ó má gbà á. Kẹ̀kẹ́ amárale koko Ṣebí àwọn ọmọdé ni wọ́n ń gun kẹ̀kẹ́? Àgbà tí ń gun kẹ̀kẹ́, àfi tí enítọ̀hún bá jẹ́ ẹlẹ́mu. [Ẹ tiẹ̀ gbọ́ ná, báwo gan-an ni àwọn ẹlẹ́mu ṣe ń gbé adúrú ẹmu yẹn káàkiri lórí kẹ̀kẹ́, tí akèrègbè ò bọ́ fọ́. Ọ̀rọ̀ ọjọ́ mìíràn nìyẹn.]. Àti pé, ojú ẹni tí ìyà ń jẹ ni wọ́n máa ń ṣábàá fi wo ẹni tí ń gun kẹ̀kẹ́ ní ilẹ̀ Yorùbá. Bí ẹni pé enítọ̀hún kò ní owó làti ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Nítorí ìdí èyí, kẹ̀kẹ́ gígùn kò wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Yoòbá. Ní abúlé, àti ìgbèríko, a lè rí àwọn àgbà tí wọ́n ń gun kẹ̀kẹ́ lọ s'óko tí ọ̀nà bá jìn. Àmọ́ ní'lùú ńlá bí Ìbàdàn, ewú ńlá ń bẹ lójú títì fún oníkẹ̀kẹ́. Yàtọ̀ fún ìwàkuwà, kò sí ìlànà àtì ètò kankan fún awákẹ̀kẹ́ lójú ọ̀nà. Ní'lẹ̀ yí kọ́! Kẹ̀kẹ́ jẹ́ nkan pàtàkì gidi fún wọn níbí. Kódà, ètò ìrìnsẹ̀ tí ìjọba pèsè fún ará ìlú – kẹ̀kẹ́ ń bẹ níbẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣìṣẹ́ ni wọ́n gbójú lé kẹ̀kẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀ná tí wọ́n fi ń dé ibiṣẹ́ wọn lójoojúmọ́. Tọmọdé tàgbà sì ní. Àwọn ọ̀dọ́langba náà gbé kẹ̀kẹ́ wọn sí ipò pàtàkì. Àti ọ̀gá ibiṣẹ́, àti ìránṣẹ́ kẹ̀kẹ́ ni ọ̀pọ̀ wọn ń gùn káàkiri bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ní'lé. Idí abájọ ni pé ètò tó péye wà fún awakẹ̀kẹ́ lójú títì. Níbìkọ̀ọ̀kan, nṣe ni wọ́n fa ààlà s'ójú ọ̀nà, tí wọ́n ya ọ̀nà kẹ̀kẹ́ s'ọ́tọ̀, tí wọ́n kùn ún ní ọ̀dà tirẹ̀ fún àkíyèsí àwọn awakọ̀ pé ọ̀nà awakẹ̀kẹ́ rèé o. Èyí dín ewu kù púpọ̀ fún ẹni tí ń gun kẹ̀kẹ́ lójú títì. Bẹ́ẹ̀náàni ọ̀pọ̀ ènìà ló ka kẹ̀kẹ́ gígùn kún eré-ìdárayá òòjọ́. Ó dára púpọ̀ fún ara ẹni, ó sì fúnni ní àlékún ìlera tó yànjú. Ẹni tí ń wa kẹ̀kẹ́ lójoojúmọ́ tó tún sanra ṣọ̀wọ́n. Ajẹ́pé enítọ̀hún a yẹra fún àwọn àìsàn tó rọ̀mọ́ sísanra bíi ẹ̀jẹ̀-ríru àti ọ̀rá-ẹ̀jẹ̀. Kẹ̀kẹ́ dára púpọ̀. Ó dùn ún gùn, a sì máa mú ara ẹni le kokooko bí ọta. Àwọn àwòrán kẹ̀kẹ́ tí mo yà láàrìn ìgbòro ni ìwọ̀nyí. Èyí tó mú mi rẹ́rìn-ín ni àwòrán olóògbé àrẹ́ Líbíà nì tí ń gun kẹ̀kẹ́ ọmọdé tí ẹnìkan fi se araògiri lẹ́ṣọ̀ọ́. Ọgbà òdòdó Ọgbà kan wà tí mo fẹ́ràn púpọ̀. Ọgbà òdòdó ni mo máa ń pè é. Kìí ṣe orúkọ rẹ̀ nìyẹn o, èmi ni mo sọ ọ́ lórúkọ bẹ́ẹ̀. ìdí ẹ̀ ni pé gbogbo ìgbà ni àwọn òdòdó aláràbarà máa ń wà nínú ọgbà náà. Kódà tí kìí bá ṣe àsìkò òdòdó rárá. A máa jẹ́ ìyàlẹ́nu fún gbogbo ẹni tó lọ síbẹ̀ nígbà tí kìí ṣe àsìkò tí àwọn òdòdó máa ń ṣábàá yọ. Ṣé ọlá àbàtà ni í mú odò ṣàn. Ọlá àwọn onímọ̀jìnlẹ̀ ọ̀gbìn tí ikọ̀ wọn ń bẹ nínú ọgbà náà ni àwọn òdòdó náà ń jẹ. Àwọn ni wọ́n máa ń gbin àwọn òdòdó nì, tí wọ́n a ṣe ìtọ́jú àti ìmójútó wọn ní inú ikọ̀ wọn, tí wọ́n á sì gbìn wọ́n sí ìta gbangba inú ọgbà náà tí wọ́n bá ṣetán. Ajẹ́pé t'òjò t'ọ̀gbẹlẹ̀ ni àwọn òdòdó ń tanná káàkiiri ọgbà náà. Tí wọ́n sì mú ọgbà náà wuni púpọ̀ púpọ̀. Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta United Kingdom kìkì ọmọ Nàìjá, pàápàá ọmọ Yorùbá. Ojoojúmọ́ ni ọkọ̀ ofurufú ń kó wọn wọ̀lú lọ́gọọgọ́rùn-ún wọn. Kíni wọ́n ń wá? Àròyé pọ̀ níbẹ̀. Ẹ jẹ́ ká mú u lọ́kọ̀ọ̀kan ní ṣókí-ṣọ́kí. Gbogbo wa la mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ọmọ Naija ni wọ́n bí sí UK, ọ̀pọ̀ náà ló sì ti di ọmọ ìlú náà nípasẹ̀ ìwé-ìgbélùú gbígbà. Àwọn wọ̀nyí ní ẹbi àti ọ̀rẹ́ tí wọ́n a máa wá bẹ̀ wọ́n wò. Ìyẹn ení. Ọlọ́run Ọba nìkan ló mọ iye ọmọ Naija to ń lọ àwọn ilé-ìwé gíga ní Orílẹ̀èdè UK lọ́dọọdún. Àwọn wọ̀nyí náà a máa gba tẹbí-tará ní àlejò láti ìgbàdégbà. Èyun èjì. Ẹlòmíràn kàn ṣeré wá láì ní ẹbí kankan tàbí ará nílùú ọba nì. Ód'ẹ̀ta. Àmọ́ àwọn tí ọ̀rọ̀ mí kàn lónìí ni àwọn oníṣòwò wa. Àwọn ti wọ́n ń torí káràkátà tẹsẹ̀ bọ ìrìnàjò àràmàndà wá sí UK. Àwọn tí wọ́n ń tọwọ́ b'àpò mú owó ọkọ̀ jáde san fún ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú. Ṣé mo ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìyànjẹ owó ọkọ̀ ofurufú nígbàkan? Owó kékeré kọ́ ni àwọn èèyàn wa ń ná dà sí ìlú yìí o. Ẹ̀yin ẹ wo ọjà kan ní Lọndọn tí àwọn èèyàn wá ń ná (àwọn àwòrán nísàlè) Ìjọba UK ni láìpẹ́, ẹnikẹ́ni láti àwọn orílẹ̀èdè mélòókan, pẹ̀lú Naijiria, tó bá fẹ́ bẹ ilẹ̀ àwọn wò, ó ní láti fí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta pọ́ùn (₦750,000) lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdánilójú pé enítọ̀hún yó padà sílé tí ọjọ́ bá pé. Wọ́n ní tí ẹni náà bá padà, àwọn yó dá owó rẹ̀ padà fún un. Àmọ́ tí ó bá tayọ ọjọ́ kan péré, owó ọ̀hún di ọ̀lẹ̀lẹ̀ tó wọnú ẹ̀kọ nìyẹn. Ṣé wọ́n ni bí kò bá ní ìdí obìnrin kìí jẹ́ Kúmólú. Àwọn òṣèlú UK fi yé aráyé pé àwọn ọmọ orílẹ̀èdè tí àwọn kà sílẹ̀ nì, wọn kò kí ń ṣábàá fẹ́ padà sílé lẹ́hìn tí àkókò tí a fún wọn ba tán. Gbogbo ènìyàn tí ọ̀rọ̀ yìí bà ké gbànjarè. Wọ́n ní ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni ìjọba UK fi ṣe. Nítorí láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀èdè tí wọ́n bá wí, kò sí ilẹ̀ aláwọ̀ funfun kankan níbẹ̀. Kíá ni ìjọba Naija náà fọhùn. Wọ́n rán UK létí pé òkò tí a sọ sí igi ọ̀pẹ ni í sọ padà sí ẹni. Kò bá rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ ni a ò bá yọ̀ pé orí àwọn olórí wa náà ti ń pé bọ̀. Ẹ jẹ́ n mẹ́nu kúro ní bẹ̀un jàre. Ní tèmi o, mo lérò pé ó yẹ ki àwọn oníṣòwò wa yé ná UK lemọ́-lemọ́. Ẹ jẹ́ kí àwa ilẹ̀ Afirika bá arawa ṣòwò, kí a máa ra ọjà arawa kí ìlọsiwájú tó péye lè dé bá wa. Kí a yé kó gbogbo owó wa wá sí òkè òkun níbi tí wọ́n ti ń yàn wá jẹ káàkiri, tí wọ́n tún ń fi ẹ̀gbin lọ̀ wá. Ẹ jẹ́ kí a yé fi ojú tẹ́mbẹ́lú nkan tiwa n'tiwa. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, irú ẹ̀gbìn yìí ò ní káwọ́ nílẹ̀ bọ̀rọ̀. Ọ̀gìnìntìn Olórí Kunkun Àsìkò ìrúwé la wà yí. Àsìkò yí ni ewé titun, ewé tútù ń so lórí igi. Ìgbà yí ni àwọn òdòdó aláràbarà ń so lórí àwọn ewéko ab'òdòdó gbogbo. Òtútù yẹ kó ti máa dínkù. Gbogbo ibi tí yìnyín ti ń rọ̀, ó yẹ kí ó ti máa dáwọ́ dúro. Kí ooru oòrùn ti máa yòòrò gbogbo omi-dídì káàkiri àgbàyé. Ní ìhà àríwá àgbáyé ni o. Àmọ́ ọ̀gìnìntìn f'àáké kọ́rí, ó l'óun ò re'bìkan. Òtútù kọ̀ ó l'óun ò ní dá gbére lótẹ̀ yìí. Ó l'óun ò ní dákẹ́ ariwo ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ tútù nini. Kàkà kó ká'gbá ń'lẹ̀ kó máa re'lé, ńṣẹ ló tún rọ funfun sílẹ̀ bí èlùbọ́. Ó fẹ́ tútù nini tí gbogbo aráyé ń gbọ̀n tí wọ́n ń wa'yín keke. Aráyé ti ìhà àríwá là ń wí sẹ́ẹ̀. Ọ̀gìnìntìn dákun kẹ́rù rẹ máa lọ. Èyí o ṣe yìí náà tó o jàre. Àṣejù baba àṣetẹ́. Jẹ́ kí àwọn òdòdó ráàyè ta. Jẹ́ kí àwọn nkan-ọ̀gbìn ráàyè yọrí jáde l'éèpẹ̀. Jẹ́ kí Alákọ̀wé ráàyè gbé ẹ̀wù kànkà yìí pamọ́ o jàre. Ara ń fẹ́ ìsinmi. Àkàrà Oúnjẹ àárọ̀ àti ìpanu àtàtà ní ilẹ Yorùbá.  Òun náà ni wọ́n ń pè ní Acarajé ní Brasil. Mo gbìyànjú ẹ̀ fúnra mi.  Kò dùn tó èyí tí ìyá mi máa ń dín, àmọ́ kò burú jù náà.  N kò rí ẹ̀kọ-mímu lọ́jọ́ náà.  Gbẹrẹfụ ni mo jẹ ẹ́ 🙂 Àwọn ẹ̀yà ẹja onírúirú Àwọn ẹ̀yà ẹja onírúirú ní wọ́n ń gbé’nú omi.  Mo lọ sí London Aquarium níjọ́sí, ibi tí wọ́n ti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ẹja aláràbarà.  Díẹ̀ nínú àwọn tó jọmí lójú nìwọnyí. iPhone Fọ́ Ní ọdún mélòókan sẹ́hìn, ẹni bá fẹ́ràn àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, nṣe ni ó ń kó wọn ká lóríṣìíríṣìí ni. Tí ẹ bá yẹ àpọ̀ enítọ̀hún wò, ẹ ó rí ẹ̀rọ ayàwòrán, ẹ̀rọ agbórinsétí alágbèéká, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́ ní òde òní, àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká tí wọ́n ń ṣe jáde ti gba'ṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé ìyókù ẹgbẹ́ ẹ wọn o. Pàápàá jùlọ iPhone àti àkójọpọ̀ àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká tí irúfẹ àìrídìmú inú wọn jẹ́ Android. A jẹ́ pé ẹ̀rọ kan ṣoṣo yìí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń gbé káàkiri. Bí a fẹ́ báni sọ̀rọ̀ ni, òun ni. Bí a fẹ́ yàwòrán ni, òun náà ni. Ìgbórinsétí nkọ́, kòsí ẹ̀rọ míì mọ́n àf'òun. Kódà, ònu ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ń yẹ Ayélujára wò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rọ ayárabíàṣá wọn. Njẹ́ mo ti wí ní ìgbàkan rí pé iPhone ni èmi gan-an alára ń lò. Gbogbo nkan sì ni mò nlò ó fún. N kò wọ ago-ọwọ́ mọ́. Orí rẹ̀ ni mo ti ń wò oun tí ago wí, òun sì ló ń jí mi láràárọ̀. Ìnú ẹ̀rọ yìí ní mo máa ń kọ gbogbo ètò sí, òun sì ni í ṣe atọ́kasọ́nà tí mo bá wà ní agbègbè ibi tí n kò mọ̀, kí n má baà sọnù. Tàbí tí mo bá ń wa'kọ̀ lọ sí ibi tí n kò dé rí. Òun ni ẹ̀rọ ayàwòrán mi. Òun ni ẹ̀rọ ìfìwéránṣẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni òun ni ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ fún mi ní ìgbà gbogbo. Ọpẹ́lọpẹ́ ọpọ́n-ìtẹ̀wé Yorùbá tó tún ń bẹ lórí ẹ̀, òun ni mo fi ń kàn sí ẹ̀yin olùkàwé mi gbogbo, yálà ní ìhà'hín ni tàbí lórí Twítà. A jẹ́ pé kòrí-kòsùn gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ èmi àti iPhone mi jẹ́ o. Arẹwà ẹ̀rọ ni iPhone jẹ́. Ìṣẹ́ ọnà gbáà ni ìṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́. Funfun rẹ̀ wà, àmọ́ dúdú bíi kóró isin ni ẹ̀rọ tèmi. Adúmáadán gidi ni nítorí pé dígí ni wọ́n fi ṣe iwájú àti ẹ̀hìn rẹ̀, wọ́n wá fi irin alárà yí i po. Sùgbọ́n ẹwà rẹ̀ yìí náà ló ṣ'àkóbá fún un o! Kàkà kí n wọ̀ ọ́ lẹ́wù tàbí kí n tì í bọ́'nú àpò fún ìdáàbò bò ó, nṣe ni mo fi sílẹ̀ ní ìhòhò. Aṣọ-káṣọ, àpò-kápò kò bá wù ó dára tó, á bu ẹwà iPhone kù ni. A jẹ́ pé nígbà tí ó ṣèṣì jábọ́ lọ́wọ́ mi níjọ́kan, tí ó sì balẹ̀ sórí àwọn òkúta, iwájú rẹ̀ tí í ṣe dígí kàn fọ́ ni. Ọpẹ́lọpẹ́ irin tí wọ́n fi dì í pọ̀, kò bá fọ́n ká pátápátá ni. A ò bá máa wá ṣa èrúnrún rẹ̀ nílẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Báyìí-báyìí ó ti wà ní ibiṣẹ́ àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ náà. Wọ́n á gbìyànjú láti tún un ṣe. Tí wọn kò bá rí i tún ṣe, wọn á fi tuntun irú rẹ̀ ránṣẹ́ sí mi. Ìdí abájọ ni pé ilé-iṣẹ́ ìfowópamọ́ ti mo ń lò máa ń yọ eélòó kan nínú owó mi lóṣooṣù. Owó yìí jẹ́ aṣèdúró fún àwọn irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ báwọ̀nyí. Iṣẹ́ ńlá ni kiní bíntín yìí ń ṣe fúni o. Ó di ìgbà ti ọwọ́ ẹni ò bá tó o mọ́ kí olúwarẹ̀ tó mọ iyì rẹ̀ o. iPhone mi ọ̀wọ́n yára máa bọ̀ wálé o! Aláwàdà lórí okùn Ẹ wo aláwàdà kan tí mo rí ní ìgboro London ní ìrọ̀lẹ́ àná. Ewu ńlá ńbẹ nínú epo-rọ̀bì! Lẹ́nu òní sí àná ni a gbọ́ pé iná jó àwọn agbègbè kan ní ìlú Èkó. Ní Èbúté Mẹ́ta, àwọn agbẹ́gità, àwọn oníṣòwò pákó àti àwọn ìran apẹja ni iná nlá kan tó jó lánàá ṣe ní jàmbá. Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n ngbé ní abúlé kan tí wọ́n tẹ̀dó sórí omi ọ̀sà ní Èbúté Mẹ́ta. Nkan tó tún ṣeni láàánú ni pé tálíkà paraku ni gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́. Oun ìní díẹ̀ tí wọ́n tún ni, àti iṣẹ́-òòjọ́ wọn náà sì ni wọ́n ti bá iná lọ. Kìí ṣe àkọ́kọ́ rèé ni Nàaìjíríà o. Àìmọye irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló nṣẹlẹ̀ káàkiri orílẹ̀ wa. Kí ọkọ̀ méjì má tíì kọlu arawọn làá ti gbọ́ pé wọ́n gbiná wọ́n sì jóná ráú-ráú lójú òpópónà. Kí ló wá fàá? Ìbéèrè yìí ò sòro dáhùn o. Ìdí abájọ ni pé nítorí kòsí ètò ìtanná tó péye ní Naija, nṣe ni olúkálukú nlo ẹ̀rọ amúnáwá fi ṣe ìtanná fúnrarẹ̀. Nkan tí ẹ̀rọ yìí nlò ṣiṣẹ́ sì ni epo-rọ̀bì. Ajẹ́ pé àwọn ènìyàn nra epo pamọ́ silé. Ẹlòmíràn lè gbé odindi garawa epo sílé! Ìdí míràn tí àwọn èèyàn ṣe máa ngbé adúrú epo báyìí sílé ni pé wọn kò mọ ìgbà tí epo lè tán ní ilé-epo, tí wọ́n sì máa láti ràá lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ntún un tà lówó iyebíye ìlọ́po méjì tàbí mẹ́ta! Tí epo bá ti wà, wọ́n á yáa rọ gbogbo ọkọ̀ àti garawa wọn kún dẹ́mú-dẹ́mú. A jẹ́ pé gbogbo àwọn agbolé ní ìlú Èkó, àti ní gbogbo Nàìjíríà lápapọ̀, kìkì epo-rọ̀bì ni. Àb'ẹ́ẹ̀ rí ewu nlá bí? Njẹ́ ó yẹ́ kí ọmọ ènìyàn máa gbé irú ìlú báyìí? Dájú-dájú ẹ̀bi ìjọba wa ni ọ̀rọ̀ yìí jẹ́. Ẹ̀kíní, tí wọ́n bá pèsè ètò-ìtanná to péye ni, àwọn èèyàn ò ní nílò àti máa gbé epo sílé rárá. Ẹ̀ẹ̀kejì, tí wọ́n bá pèsè epo-rọ̀bì tó káárí gbogbo gbòò, wọ́n á yéé gbé èpò sẹ́hìn ọkọ̀ rìn. Eléyìí á dẹ́kun ọkọ̀ gbígbiná lójú títì. Àmọ́ àwọn ọmọ Naija náà kó díẹ̀ nínú ẹ̀bi o. Oríṣìíríṣìí ìkìlọ̀ ló ti bọ́ sí etí i wọn nípa ewu tí nbẹ nínú epo-rọ̀bì, ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pé bí ọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣe ngba etí ọ̀tún wọlé ni ó ngba etí òsì jáde. Ẹni a wí fún, Ọba jẹ́ ó gbọ́. Èyí tí ò gbọ́ nṣe'rarẹ̀. Ó tó ṣe bí òwe. Àwọn ọkọ̀ àti kẹ̀kẹ́ akérò ní Ìlú Èkó Nkankan tó wùmí ní ìlú Èkó ni bí wọ́n ṣe kun gbogbo ọkọ̀ àti kẹ̀kẹ́ akérò ní ọ̀dà kannáà.  Èyí máà nmú kí gbogbo wọn bárawọn mu dáadáa kí wọ́n sì gúnrégé lójú, bíótilẹ̀jẹ́pé púpọ̀jù nínú wọn ti fẹ́ẹ̀ẹ́ bàjẹ́ tán.  Ó dàbí bí wọ́n ṣe kùn wọ́n náà ní ìlú New York ni.  Kì báà jẹ́ pé àwọn ọkọ̀ tiwọn tuntun nini yàtọ̀ sí tiwa 🙂 Ajíṣe bí Ọ̀yọ́ làá rí Lónìí òpin ọdún 2012, tí a bá bojú wẹ̀hìn, a ó rí i pé ọ̀pọ̀ òjò ló ti rọ̀ lọ́dúnnìí, tí ilẹ̀ sì fi mu. Oríṣìíríṣìí nkan olókìkí ló ti ṣẹlẹ̀ ní Naijiria àti ni gbogbo àgbáyé. Àwọn nkan rere àti àwọn nkan búburú pẹ̀lú. Ọdún 2012 ni ìdíje Olympics wáyé ní ìlú Lọndon. Ọdún yìí náà ni wọ́n tún Obama yàn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹrika. Àwọn ìròhìn ayọ̀ oníkanòjọ̀kan náà la gbọ́ káàkiri àgbáyé. Àmọ́ o, bí ó ti ntutù níbìkan ní í gbóná ní ibòmíràn. Àìmọye jàmbá la gbọ́ pé ó ṣelẹ̀ káàkiri àgbáyé lọ́dúnnìí. Ẹnìkan ló fi ikú ìbọn rán àwọn ọmọdé kékeré lọ sọ́run òjijì ní Amẹrika ni ìjọ́sí. Bẹ́ẹ̀náàni ààrẹ orílẹ̀ Síríà kò dáwọ́ pípa àwọm ọmọ ìlú rẹ̀ dúró. Àwọn ìjì nlá-nlá tún jà káàkiri àgbáyé, tí wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá lọ́. Ní Naija, ọkọ̀ òfurufú kò yéé jábọ́. Àwọn òlóṣèlú oníwàìbàjẹ́ ò yéé hùwà wọn. Àmọ́n èyí tó kanni lóminú jù ni ti àwọn alákatakítí Boko Haram, tí wọ́n ndúnbú ọmọ ènìyan bí eran lásán. Ṣùgbọ́n ìrírí ayọ̀ ni tiwa ní ilẹ̀ Yorùbá ni ti ẹlẹ́sìn dé o. Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ẹlẹ́sìn Kiristẹ́nì àti Mùsùlùmí kìí bárawọn ṣe dáadáa ní gbogbo ibòmíràn, irẹ́pọ̀ gidi ló wà láàrin àwọn ẹlẹ́sìn méjéèjì ní ilẹ̀ Káàárọ̀-oòjíire. Kò ṣọ̀wọ́n ká rí ṣóòṣì àti mọ́ṣáláṣí tí wọ́n kọ́ si ẹ̀gbẹ́ arawọn. Ka rí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ to já èrò sílẹ̀, kí lágbájá kọrí sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ ké alelúyà, ki tẹ̀mẹ̀dù náà sì gba mọ́ṣáláṣí lọ rèé ké láìláà. Bó ti rí gẹ́lẹ́ ní ilẹ̀ Yoòbá nìyẹn láìsí ìjà, láìsí rògbòdìyàn. Ní ọdún 2013 tó wọlé dé yìí, aríkọ́ṣe àti àwòkọ́ṣe ni ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ fún gbogbo àgbáyé nípa ìrẹ́pọ̀ èsìn. “Ajíṣe bí Ọ̀yọ́ làá rí o….” Kí gbogbo wa káàkiri àgbáyé jáwọ́ nínú ìwa ẹlẹ́sìnmẹ̀sìn tó nkó jambá nlá ba ilé-ayé yìí. Ọlọ́run níkan ló mọ ẹni tí ó là o. Ìwé Afọ́jú Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan báyìí nínú ọkọ̀-ojúurin abẹ́lẹ̀ ní ìlú Paris, ọ̀gbẹ́ni afọ́jú kan fẹ̀lẹ̀ jókòó sórí ìjòkó tó kọjú sí mi. Ọjọ́-orí ọkùnrin náà a jẹ́ nkan bíi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ọgbọ̀n. Ẹ̀yà adúláwọ̀ ni ọkùnrin náà jẹ́. Enìyàn kúkúrú sì ni. Kòsí ẹnikẹ́ni tí ó nràn án lọ́wọ́, kò sì ní ajá-afọ́jú rárá, àfi ọ̀pá-afọ́jú tí o mú dání. Síbẹ̀-síbẹ̀ afọ́jú náà wọ ọkọ̀ akérò láìsí ìṣòro kankan. Nígbà tó ṣe díẹ̀ tí a ti wà nínú ọkọ̀ náà, mo ṣe àkíyèsí pé afọ́jú náà nrọra rẹ́rìn-ín sí'ra rẹ̀. Kò dẹ̀ sí ẹnikẹ́ni tó nsọ̀rọ̀ síi. Àmọ́ nígbà tí mo wo ibi ọwọ́ rẹ̀ wà, mo rí kiníkan pẹlẹbẹ tó gbé lé itan, tí ó nfi àwọn ìka ọwọ́ rẹ̀ kan. Kíni ọ̀hún dàbí ìwé ṣùgbọ́n tí wọn kò kọ nkankan sí. Nígbà ti mo wòó dáadáa ni mo wá rí i pé wọ́n lu àwọn ihò wíní-wíní sí gbogbo ojú ìwé náà. Àmọ́ ẹ̀hìn ojú ewé ìwé ni wọ́n lu'hò sí; ajẹ́ pé ní iwájú ojú-ewé ìwé, ihò kọ̀ọ̀kan rọra lé sókè. Lílé sókè àwọn ihò náà ni afọ́jú nfi ọwọ́ kàn lójú ewé ìwé náà. Kí wá ló fa ẹ̀rín-àdárín afọ́jú? Ìwé mà ló nkà o. A jẹ́ pé ó ka nkan tó pàá lẹ́rìn-ín nínú àkọsílẹ̀ tó nkà ni. Báwo wá ni afọ́jú ti nrí ìwé kà? Àbí ojú kọ́ la fi nkàwé ni? Ìdí abájọ ni pé àwọn ihò ojú-ewé náà, álúfábẹ́ẹ̀tì àti ònkà afọ́jú tí wọ́n npè ní Braille ni wọ́n jẹ́. Ọ̀gbẹ́ni Loiuse Braille tí í ṣe ọmọ orílẹ̀èdè Faransé ló ṣètò álúfábẹ́ẹ̀tì yìí fún àwọn afọ́jú ní ọdún 1821. Òun gangan kọ́ ló kọ́kọ́ ṣẹ̀dá irúfẹ́ ọ̀nà àti kàwé báyìí o. Ọ̀gbẹ́ni Charles Barbier láyé ààrẹ Napoleon Bonaparte ló kọ́kọ́ ṣe irú ẹ̀. Napoleon paá láṣẹ fún àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n àti onímọ̀ orílẹ̀èdè rẹ̀ pé kí wọ́n wá ọ̀na tí àwọn jagunjagun òun lè fi máa kàwé nínú òkùnkùn láì tan iná kalẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Barbier ló dáhùn ìpèníjà yìí nígbà náà. Méjìlá-méjìlá ni ó to àwọn ihò tiẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́. Sùgbọ́n nígbà tí àwọn jagun-jagun ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ̀, wọ́n kọ̀ọ́. Wọ́n wípé ó ti ṣòro jù látì kà nítorí ihò méjìlá ti pọ̀jù láti fi ìka ènìyàn kàn lẹ́ẹ̀kannáà. Lẹ́hìn ìgbà yí ni Ọ̀gbẹ́ni Barbier bá Ọ̀gbẹ́ni Braille pàdé ní ìlú Paris ní ọdún 1821 nígbàtí ó ṣe àbẹ̀wò ló sí ilé-ẹ̀kọ́ àwọn afọ́jú. Louise Braille ló wá ṣe àtúnṣe sí ètò ihò-títò náà. Ó dín in kù sí ihò mẹ́fà-mẹ́fà, ó sì ṣé e to fi bá álúfábẹ́ẹ̀tì Faransé mu. Ìdí èyí ni wọ́n fi npèé ní Braille. Ọdún 1905 ni wọ́n tó ṣe irúfẹ́ rẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì. Láyé òde òni o, Braille yìí tí wọ́pọ̀ lóríṣìíríṣìí èdè káàkiri àgbáyé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé sì ni wọ́n ti fi Braille tẹ̀ jáde fún ẹ̀kọ́ àti ìgbádùn àwọn afọ́jú. Eléyìí tún fún àwọn afọ́jú ní ànfàní àti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè, tàbí láti ka ìwé ẹ̀sìn wọn bíi Bíbélì àbí Àlùkùránì. Kódà, ní àwọn orílẹ̀èdè tó lajú dáadáa, àwọn òfìn kọ̀ọ̀kan wà láti mú ìrọ̀rùn bá àwọn àkàndá ẹ̀dá bí àwọn afọ́jú. Nínú àwọn òfin wọ̀nyí ni pé kí wọ́n máa kọ Braille sára àwọn nkan bíi agolo òògùn, kí àwọn afọ́jú fi lè ríi kà fúnra wọn. Bẹ́ẹ̀náàni onírúirú ẹ̀rọ ìgbàlódé ti njáde fún àwọn afọ́jú. Ẹ̀rọ ayárabíàṣá oní Braille náà nbẹ! Àṣé bí ọkùnrin afọ́jú náà ṣe nkàwé lọ, ó tún fi etí sílẹ̀ sí ìkéde awakọ̀ èrò. Nígbà tó yá ló bá yára palẹ̀ ìwé rẹ̀ mọ́, ó mú ọ̀pá rẹ̀, ó dìde ó rìn tààrà jáde kúrò nínú ọkọ̀ náà láìsí ìràlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. Èmi ntèmi, ọkọ̀ ti kọja ibi tí mò nlọ. Mo ti wòran lọ. Àwọn ọmọdé kú ikú ìbọn : Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan ló ṣẹlẹ̀ ní ìlú Newton ní ìpínlẹ̀ Connecticut ní àárọ̀ ọjọ́ Ẹtì tó k��já o. Orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà ni ìpínlẹ̀ náà wà. Ọkùnrin ọmọ ogún ọdún kan ló gbé ìbọn ìyá rẹ̀, tó sì yin ìyá rẹ̀ pa nínú ilé wọn. Lẹ́hìn èyí ló tún gbéra o kọrí sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí ìyá rẹ̀ ti jẹ́ olùkọ́. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ìyá rẹ̀ ló wà débẹ̀, ó sì kó ibọn oríṣìí mẹ́ta dání. Ìlé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí njẹ́ Sandy Hook ni ọkùrin aṣebi yìí ti da ìbọn bo àwọn ọmọdé kékèké tí ọjọ́-orí wọn jẹ́ mẹ́fà àti méje. Ogún ọmọdé ni wọ́n kú ikú oró lọ́wọ́ ìkà ọkùnrin lọ́jọ́ náà. Kò bá jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn olùkọ́ ti wọn ṣe takun-takun làálàá láti dáàbò bo àwọn ọmọdé. Àwọn tí wọ́n ráàyè sá àsálà fún ẹ̀mí wọn sá síta kíákíá kúro nínú ewu ìbọn náà. Bẹ́ẹ̀ púpọ̀ nínú àwọn olùkọ́ náà ni wọn fara gbọta. Àwọn olùkọ́ mẹ́fà ni wọn sì gba ibẹ̀ ṣaláìsí. Isẹ́jú mẹ́wàá péré lo kọjá ti àwọn ọlọ́pàá fi dé tìbọn-tìbọn, ṣùgbọ́n eléyìí ti pẹ́ jù. Ọkùnrin náà ti pa púpọ̀ núnú àwọn ọmọdé àti àgbà, ó sì ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ léṣe. Àti pé ó kanlẹ̀ ti kọjú ìbọn sírarẹ̀, ó ti dágbére sí ilé-ayé kí àwọn agbófinró tó dé. Ìbànújẹ́ nlá ni eléyìí jẹ́ fún gbogbo ará ìlú àti gbogbo Amẹrika lápapọ̀. Ààrẹ Obama ti ṣe ìkéde nípà ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó wípé ọ̀rọ̀ yí ba òun nínú jẹ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ̀ Amẹrika, àti gẹ́gẹ́ bíi baba ọmọ méjì fúnra òun. Omi fẹ́ máa bọ́ lójú rẹ̀ bí ó ṣe nṣe ìkéde náà. Ìwádìí ìjìnlẹ̀ ni ó ti bẹ̀rẹ̀ báyìí láti rí kíló lè fa kí ọkùnrin apààyàn náà kọjú ìbọn sí àwọn ọmọdé tí wọ́n kéré báyìí. Àti pé irúfẹ́ àwọn ìbọn tó lò mú kó lè pààyàn kíákíá nítorí àwọn ìbọn alágbára ni ó lò. Àwọn ìbọn náà sì gba ọgbọ̀n ọta lẹ́ẹ̀kannáà. Òfin Amẹrika gbàá láàyè fún ẹnikẹ́ni láti ní ìbọn. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí ìyá ọkùnrin apànìyàn náà fi ní ìbọn nílé, tí ọwọ́ ọmọ rẹ̀ fi tẹ̀ẹ́. Àwọn olóṣèlú kọ̀ọ̀kan ti fipá mú ààrẹ Obama pé kó tiraka láti yí òfin náà pádà, kí wọ́n fi lè dẹ́kun àwọn íṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí nítorí kìí ṣe àkọ́kọ́ rẹ̀ nìyí. Ṣùgbọ́n á ṣòro fún Obama nítorí pé àwọn olóṣèlú míràn gbàgbọ́ pé ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ Amẹrika ni láti ní ìbọn. Wọ́n ní bí àwọn babánlá àwọn tó tẹ ilẹ̀ Amẹrika dó ṣe fẹ́ ẹ nìyẹn. Àmọ́ àwọn ìdàkejì wí pé láyé àtijọ́, kò tíì sí àwọn ìbọn alágbára ti òde òni. Gbogbo àgbáyé ló bá Orilẹ̀èdè Amẹrika kẹ́dùn. Iṣẹ̀lẹ̀ burúkú gbáà lo ṣẹlẹ̀ yìí. Kí Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ àwọn tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn. Kí Olódùmarè má jẹ́ káa rí irú èyí mọ́ láíláí. Òní jẹ́ ọjọ́ kejìlá, oṣù kejìlá, ọdún kejìlálélẹ́gbàá. Káàkiri àgáyé ni àwọn èèyàn dá ọjọ́ òní sí ní ọlọ́kan-òjọ̀kan nítorí bí ònkà ọjọ́ náà ṣe báramu rẹ́gí-rẹ́gí. Ìyàtọ̀ wà láàrin bí wọ́n ṣe nkọ ọ́ ní ìlànà Amẹ́ríkà àti ti àwọn Oríẹ̀èdè ìyókù. Ní Amẹ́ríkà, ònkà oṣù ni wọ́n máa nkọ ṣáájú ònkà ọjọ́. Ní gbogbo ibòmíràn ẹ̀wẹ̀, ònkà ọjọ́ ní í ṣíwájú kí ti oṣù tó tẹ̀lé e. Àmọ́ lọ́jọ́ òní, ìlànà méjéèjì náà tún báramu. Tí aago méjìlá bá tún wá kọjá ìṣẹ́jú méjìlá àti aaya-ìṣẹ́jú méjìá, gbogbo rẹ̀ a wá báramu rẹ́gí-rẹ́gí tán pátá-pátá poo. Wọ́n ní àkókò kò dúró de ẹnìkan. Gbàrà tí àkókò yìí bá dé, ó ti tún sáré tẹ̀ síwájú, ó nbá’bi tiẹ̀ lọ. Ó tún di ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún, ní ọjọ́ kíní, oṣù kíní ọdún 2101, tí kíkọ sílẹ̀ rẹ̀ á jẹ́ 01/01/01. Àyàfi ọmọ tuntun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sáyé, àti àwọn tí Olódùmarè bá fún ní ẹ̀mí gígùn gbọ̀rọ̀-gbọrọ, ṣàṣà ni ẹni tí ò ní tíì jẹ́ ìpè Ẹlẹ́dàá rẹ̀ kí ìgbà náà tó dé o. Ìyẹn tí ayé gan-an kò bá tíì parẹ́. Ọjọ́ mẹ́wàá péré lókù Àwọn ẹ̀yà ayé àtijọ́ kan tí wọ́n pe orúkọ wọn ní Maya sọ wipé ayé á parẹ́ ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kejìlá ọdún 2012. Ọjọ́ mẹ́wàá òní ni ọjọ́ náà pé o! Njẹ́ lóòótọ́ ni ayé máa parẹ́ bí? Bótilẹ̀jẹ́pé àwọn ẹ̀yà Maya ti parẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé ní nkan bíi ��gbẹ̀rún ọdún sẹ́hìn, òkìkí wọn ti kàn gidi gidi lọ́dúnnìí nítorí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọn yìí. Lóòtọ́ ná, bí eré bí àwàdà ni púpọ̀ nínú wa fi nṣe, àmọ́ àwọn kan ní ìgbàgbọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, wọ́n ti lọ́ ba sórí àwọn àpátá nlá-nlá. Irú èyí nṣẹlẹ̀ lọ́wọ́-lọ́wọ́ ní ìlú Faransé, Séríbíà, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní tèmi o, mo mọ̀n dájú pé kòs'ẹ́ni mọ̀la. Ṣùgbọ́n ó múmi ronú pé tí ayé bá máa parẹ́ kí Kérésì tó dé, njẹ́ èmi ti ṣetán láti pàdé Ẹlẹ́dàá báyìí? Àti pé kíló kù nlẹ̀ tí ng kò tíì ṣe? Ìyànjẹ Owó Ọkọ̀ Òfurufú Àyájọ́ Ọjọ́ Àrùn Kògbóògùn Oun tó bá léni léni tí kò ríni mú, ṣèbí òun ni Ìmúnitì. Àbí? Ilé-aiyé kún fún àìmọye àrùn tí nbá ọmọ ènìà jà. Púpọ̀ nínú àwọn àrùn wọ̀nyí, àwọn kòkòrò tí a kò lè fi ojú lásán rí ni wọ́n nfà wọ́n. Tí kìí bá ṣe fún ìṣẹ̀dá ara ọmọ ènìà ni, a kò lé gbé ilé-aiyé yìí ju ọjọ́ méjì sí mẹ́ta lọ. Yàtọ̀ sí ògùn tí a nlò láti mú ara wa dá tí ó bá rẹ̀wá, àgọ́ ara wa gan-an kún fún àwọn ọmọ-ogun tí wọ́n ndáàbò bo ara wa. Àwọn ọmọ-ogun yìí máa nbá àwọn kòkòrò aṣekúpani jà tí wọ́n bá wọnú àgọ́ ara wa. Ìyẹn ni pé wọ́n wà fúnwa gẹ́gẹ́ bí àjẹára ni. Àwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan wà nínú ara wa tí iṣẹ́ wọn jẹ́ pípèsè àti dídarí àwọn ọmọ-ogun ara náà. Tí àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí bá kófìrí àwọn kòkòrò aṣekúpani nínú àgọ́ ara, kíákíá ni wọ́n máa da àwọn ọmọ-gun síta kí wọn lọ dojú ìjà ko wọ́n. Nígbà míràn àwọn ògùn tí a nlò dà bí irinṣẹ́ àti nkan ìlò ogun fún àwọn ọmọ-ogun ara wa. Á jẹ́ bí ìrànlọ́wọ́ fún wọn láti ṣẹ́gun àwọn kòkòrò amúniṣàárẹ̀ tí wọ́n nbá jà. Àmọ́ kòkòrò ju kòkòrò lọ. Irúfẹ́ kòkòrò aṣekúpani kan wà tí wọ́n npè ní HIV. Tí HIV bá wọnú àgọ́ ara tán, àwọn ẹ̀yà ara tí wọ́n npèsè ọmọ-ogun ara ní í bájà. Díẹ̀ díẹ̀, á máa dín agbára ara ẹni láti dáàbò bo ararẹ̀ kù. Tó bá dínkù dé'bìkan tí kòsí àjẹára fún ènìà mọ́, wọ́n á ní olúwarẹ̀ ní àrùn Kògbóògù, tí wọ́n npè ní AIDS. Ajẹ́pé ara ẹni kò lè bá nkankan jà mọ́. Àìsàn tí kò tó nkan ní í ránni lọ s'álákeji. Ìyẹn ni pé AIDS fúnrarẹ̀ kọ́ ni nsẹkú pani, bí kìí ṣe ìyà nlá tó gbéni ṣánlẹ̀, tí kékèké wá ngorí ẹni. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún fẹ́ ṣe bí òwe. Akitiyan nlá ni àwọn onímọ̀ iṣègùn àti oníwàdìí-jinlẹ̀ ilera ti ṣe káàkiri àgbáyé láti wá ògùn tó kápá àrùn yìí. Ìlọsíwájú sì ti wà dájú-dájú, ṣùgbọ́n kò tíì sí àwárí kankan tó kápá àrùn kògbóògùn pátápátá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìà ló sì ti ti ipasẹ̀ àrùn yìí rè'wàlẹ̀àsà. Ní ọdún 1988 wọ́n dá ọjọ́ kíní ọsù Ọpẹ sí gẹ́gẹ́ bíi Ọjọ́ Àrùn Kògbóògù Àgbáíyé. Nkan mẹ́ta ni ọjọ́ náà wà fún. 1. Ìrántí àwọn tí wọ́n ti di olóògbé nípasẹ̀ àrùn Kògbóògun, àti àwọn tí wọ́n ngbé pẹ̀lú kòkòrò àrùn náà nínú ara wọn. 2. Ìfihàn àtìlẹ́hìn àti ìbásowọ́pọ̀ àti ìrànlọ́wọ́ fún akitiyan àwọn tí wọ́n nṣe ìwádìí tó jẹmọ́ àrùn Kògbóògùn. 3. Láti ṣe ìtànká ìmọ̀ nípa àrùn Kògbóògùn, àti láti ṣe ìkìlọ̀ fún gbogbo gbòò nípa àrùn náà. Ọjà Kérésìmesì Jamani Gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn ní Lọndon lọ́dọọdún tí Kérésìmesì bá ti nsúmọ́, Ọgbà Hyde Park ti paradà di Winter Wanderland. Ìlú Jamani ni wọ́n ti kọ́ àṣà yìí, ó dẹ̀ hàn gedegbe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ọjà-kérésìmesì-Jamani ni wọ́n npèé. Nkan oníkanòjọ̀kan àti onírúirú ló wà níbẹ̀ fún ìgbádùn tọmọdé tàgbà. Oríṣìíríṣìí onjẹ ni ènìyàn lè rí ràjẹ pẹ̀lú, pàápàá láti ìlú Jamani. Ọtí kan wà níbẹ̀ tí wọ́n npè ní mulled wine tó gbọ́nà fẹli-fẹli. Ọtí náà wọ́pọ̀ ní mímu nígbà òtútù ọ̀gìnìntìn ní orílẹ̀ Jamini àti káàkiri Úróòpù. Nkan bí oṣù kan àbọ̀ ni ọgbà yìí ṣí fún. Ìyẹn ni pé ènìyàn ní ànfàní àti lọ síbẹ̀ títí di ọdún tuntun. Àmọ́ ìkìlọ̀ nlá rèé o: ẹni bá fẹ́ lọ kó yàá mú owo lọ́wọ́ o, nítorí nkan rọra gbówó lórí díẹ̀ níbẹ̀. Kí enítọ̀hún sì dì-káká dì-kuku bíi Baba Sùwé kó má baà ganpa nínú òtútù! Kẹ̀kẹ́ Marwa Yàtọ̀ sí Ọkada tí í ṣe kẹ̀kẹ́ akérò alùpùpù ní Naija, kẹ̀kẹ́ Marwa – kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta ní í ṣe. Kẹ̀kẹ́ náà ti gbajú-gbajà ní ìlú Èkó àti awọn ìlu nlá-nlá kọ̀ọ̀kan káàkiri Naija. Lati orúkọ Mohammed Buba Marwa tí ó jẹ́ gómìnà Èkó nígbàkan ni orúkọ kẹ̀kẹ́ yìí ti jẹyọ. Àwọn òpópónà àti títì kékeré nìkan ni òfin gba kẹ̀kẹ́ Marwa láàyè àti rìn. Ìdí ẹ̀ ni pé kò lágbára títì nlá rárá. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ nígbàtí akérò kan ṣàìgbọràn, tí ó ngbé èrò lọ lórí títì nlá tó lọ́ sí Ibadan láti Èkó. Ọkọ̀ akẹ́rù gbàngbà kan sáré kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Atẹ́gùn ọkọ̀ akẹ́rù náà lásán ló fẹ́ kẹ̀kẹ́ Marwa kúrò lójú títì tó fi forí sọ òpó kan, tí awakẹ̀kẹ́ àti àwọn èrò fi ara pa. Nkan bí ọdún méjì sẹ́hìn ni mo ya àwòrán yìí ní àdúgbò Èbúté Mẹ́ta ní ìlú Èkó. Bíótilẹ̀jẹ́pé púpọ̀ nínú àwọn kẹ̀kẹ́ Marwa náà ti gbo ti wọ́n ti fẹ́ẹ̀ẹ́ bàjẹ́, tí wọ́n sì rí jáku-jàku, wọ́n kópa pàtàkì nínú ètò-ìrìnsẹ̀ àwọn ará ìlú, pàápàá jùlọ fún àwọn mẹ̀kúnù. Àti pé bí wọ́n ṣe kùn wọ́n ní ọ̀dà àláwọ̀ kánnáà jẹ́ kí wọ́n dùn-ún wò lójú. Ní èrò tèmi o, wọ́n bu ẹwà kún ìlú Èkó rẹpẹtẹ! Ìjọba amúnisìn tuntun nbọ̀ Alágbára ni àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá nṣe nígbàkan rí. Pàápàá àwọn Aláàfin Ọ̀yọ́. Ìjọba amúnisìn sì ni wọ́n jẹ́ nígbànáà fún àwọn ẹ̀yà tó yí ilẹ̀ Yorùbá po. Ọba ilẹ̀ Yorùbá ni olùṣàkóso gbogbowọn, tí wọ́n sì nsan ìsákọ́lẹ̀ fún àwọn Ọba olókìkí náà. Ọba mẹ́wàá ìgbà mẹ́wàá, wọ́n l’óun ló ni ilé-ayé. Ìgbà yí padà fún ẹ̀yà Yorùbá nígbà ayé ọba Arólẹ̀ àti ààrẹ ọ̀nà kakanfò Àfọ̀njá. Àìṣọ̀kan ọmọ Oòduà kó wọn lẹ́rù fún Fúlàni. Ṣèbí tí ìyà nlá bá gbeni ṣánlẹ̀, kékèké a sì máa gorí ẹni. Nígbà tó tún yá, ọkọ̀ ojú omi tún gbé jàmbá nlá dé. Àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun kówa lọ sí oko ẹrú lẹ́hìn-ọ̀rẹhìn, wọ́n sì pín àwa ìyókù ní Afirika wẹ́lẹwẹ̀lẹ mọ́nrawa. Ìjọba òyìnbó amúnisìn náà la ò bá gbọ́njú bá, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ènìyàn pàtàkì tí wọ́n ṣe làálàá, tí wọ́n ja ìjà òmìnira takun-takun. Bíótilẹ̀jẹ́pé òmìnira ọ̀hún gan-an ò péye, ìyẹn ni pé òmìnira ìjọba lásán ni kòsí òmìnira ọrọ̀-ajé di òní-olónìí. A bọ́ lọ́wọ́ ẹkùn bọ́ sọ́wọ́ ònì ni. Àwọn ìjọba ológun wá sọ ìṣèlú ilẹ̀ Afirika di pàsí-pàrọ̀. Wọ́n kó gbogbo ti’lé tà tán, gbogbo orílẹ̀ tí í ṣe ti adúláwọ̀ wá kó si gbèsè rẹpẹtẹ. Wọ̀bílíkí wá nyàgò fún wọ̀bìà. Ẹnu ẹ̀ lá wà báyìí-báyìí tí aṣeni fi ṣílẹ̀kùn ẹ̀hìnkùlé fún ọ̀tá! Ọ̀tá tí wọn kò kanlẹ̀ ṣílẹ̀kùn fún gan-an, díẹ̀ díẹ̀ ni imú ẹlẹ́dẹ̀ nwọ’gbà. Wọ́n ní pánsá ò fura ó já, àjà ò fura ó jìn. Ọmọ Yorùbá, àti gbogbo adúláwọ̀ ẹgbẹ́ ẹ wa, a ti sùnlọ. A sùn gbàgbé iná táa gbé sórí òrùlé. Iná ọ̀hún ti wá ran’lé wàyí, ó ti bọ́ sára aṣọ. Àjèjì tuntun tó wọlé yìí, bí ó ti ngbé ewúrẹ ní í gbé àgùntàn. Ẹlòmíràn kanlẹ̀ ta ilẹ̀ baba rẹ̀ fún un ni l’ówó pọ́ọ́kú. Àti baálé àti baálẹ̀ ni wọ́n nyọ̀mọ́ ọn. Wọ́n nhùwà aláìgbọ́n nítorí oun tí wọ́n ó jẹ ni wọ́n nwá. Wọ́n ti gb’owó ẹ̀yìn lọ́wọ́ àlejò. Àjèjì ti da omi síwájú rẹpẹtẹ fúnrarẹ̀. Ó ku kí ó máa tẹ ilẹ̀ tútù. Àmọ́ omi’gbóná lèyí jẹ́ lẹ́sẹ̀ ọmọ Oòduà onílé. Nítorí oun tó kọ iwájú sẹ́nìkan, ẹ̀yìn ló kọ sẹ́lòmíì. Èmi ò kúkú dá àjèjì yìí l’ẹ́bi. Ṣèbí ìlọsíwájú ìran àti ẹ̀yà tirẹ̀ ló nwá kiiri. Ó sì rìnnà ko ibi tí Ọlọ́run dá lọ́lá, ṣùgbọ́n tí àwọn èdá ibẹ̀ kò bìkítà rárá. Àfi kí wọ́n máa bá arawọn jà lójoojúmọ́. Kìí ṣe ẹjọ́ àlejò yìí rárá. Ta ni yó wa tawá jí pẹ́pẹ́ kúrò lójú orun òfò yìí adúláwọ̀? Àbí ṣe ibẹ̀ làá wà tí ìjọba amúnisìn míràn á tún fi dé bí? Ilé tó nléfò nínú igbó Ni ọ̀sẹ̀ tó kọjá, èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi kan rin ìrìnàjò-ìgbafẹ́ lọ sí ìgbèríko kan. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ló wọ́pọ̀ jù ní ìgbèríko náà, ó sì ṣe kìkì igbó àti oko. Onírúirú nkan ọ̀gbìn àti èso ni àwọn àgbẹ̀ náà ngbìn, wọ́n sì nsin oríṣìíríṣìí ẹranko. Màlúù, ẹlẹ́dẹ̀, tòlótòló àti adìẹ n'ọ́n pọ̀jù nínú àwọn ẹranko tí àwọn àgbẹ̀ ìgbèríko náà nsìn. Òwúrọ̀ kùtù-kùtù kan ni èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi wọ̀nyí gbéra, tí a kórí sí inú igbó kan. Bótilẹ̀jẹ́pé ojú-ọjọ́ ṣe bí ẹní fẹ́ rọ̀'jò, nkan táa lọ ṣe níbẹ̀ náà ni àrìnká káàkiri inú igbó àti pákáko ẹ̀bá ìgbèríko ọ̀hún, gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa bí onírìnàjò. Kò pẹ́ díẹ̀ táa rìn nínú igbó náà dé'bìkan ni mo pe àkíyèsí àwọn ẹlẹgbẹ́ mi sí nkankan tí mo rí lókèrè. Àwọn igi àti ewéko kan díwa lójú díẹ̀ tí a kò sì rí nkan náà dáadáa. A bẹ̀rẹ̀ sí í súnmọ́ ọn káa fi lè ríi dáadáa. Nígbà tí a súnmọ́ nkan náà dé ibi pé kò sí nkankan tó díwa lójú, tí a sì nwòó kedere ní iwájú wa, ìyanu gbáà ló jẹ́ fún wa. A wo arawa pé àbí irọ́ ni, kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ilé kan lá mà rí o. Irin ni wọ́n fí kọ́ ilé náà. Àmọ́ nkan tó jẹ́ ìyanu nlá fún wa ni pé ní àkọ́kọ́ ilé náà dàbí eni pé ó léfò lórí afẹ́fẹ́ ni! ṣùgbọ́n nígbà tí a wòó tí a tún-un wò, a ríi pé nṣe ni ilé náà fi igun kan kanlẹ̀. Àmọ́ o, igun kan tó fi kanlẹ̀ kò dín ìyanu náà kù rárá. Nítorí a wòó pé o yẹ kí ilé ọ̀hún wó lulẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ tó léfò. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀. Nṣe ni ilé náà dúró gbain-gbain bí igi osè ni. Kódà wọ́ tún ta okùn mọ́ abẹ́ ilé náà níbi to ti léfò, tí wọn sì ṣe ìjókòó olókùn sí i! A tún fojú inú ròó pé ẹni bá jókòó sórí okùn náà, àfi kí ilé wó lu olúwarẹ̀ pa. Kíkọ́ tí wọ́n kọ́ ilé náà sí inú igbó tún yàwá lẹ́nù díẹ̀. A wò ráràrá bóyá a ó rí ẹnìkan níbẹ̀, ṣùgbọ́n ibẹ̀ dákẹ́ rọrọ ni. Àwa nìkan sì là wà ní àdúgbò náà. Ṣé wọ́n ní “igi gogoro má gúnmi lójú, àtòkèrè làá tí í wòó” àbí? Òun ló dífá fún wa lọ́jọ́ náà, táa fi tẹsẹ̀ mọ́nrìn kúrò nínú igbó náà, táa darí sí ìgbèríko táa fi ṣe ibùdó. Nigbàtí a dé ìgbèríko náà ni a wá fi ọ̀rọ̀ wá àwọn ará ìlú lẹ́nu wò nípa ilé tó nléfò nínú igbó. Ẹ̀rín ni wọ́n fi wá rín nígbàtí wọ́n ṣàkíyèsí pé ó bàwá lẹ́rù díẹ̀. Wọ́n sọ fún wa pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ ilé-kíkọ́ kan ni wọ́n kọ́ ilé náà síbẹ̀. Wọ́n ní ara nkan tí ó nfa èrò wá sí ìlú àwọn nìyẹn. Kódà wọ́n ní ènìyàn lè sanwó ránpẹ́ kan tí ènìyàn bá fẹ́ dúró síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ibùgbé. Nígbàtí èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi dé'lé a se ìwádìí nípa ilé náà lórí Ayélujára. Bí àwọn ará ìgbèríko náà ti wí bẹ́ẹ̀ náà ló rí. Àb'ẹ́ẹ̀ rí nkan? Yoòbá ní “Àìrìn jìnnà ni ò jẹ́ ká rí abuké ọ̀kẹ́rẹ́, táa bá rìn jìnnà à ó rí abuké erin”. Yoòbá kú ọ̀rọ̀. Ìdìbò ààrẹ Amẹrika Òní lọjọ́ pé ti àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Amẹrika nyan ààrẹ orílẹ̀èdè sípò nínú ìdìbò gbogbo gbòò. Àwọn òṣèlú tí wọ́n ndu ipò yìí pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn méjì péré ni wọ́n jẹ́ asíwájú. Ìkíní ni ààrẹ òní Barak Obama. Ìkejì ni ọ̀gbẹ́ni Mitt Romney tí í ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Massachusetts. Èyí tó bá wù kó wọlé, pàtàkì rẹ̀ ni pé kí olúkálukú tó bá lẹ́tọ̀ọ́ ìdìbò kó jáde lọ dìbò. Pàápàá jùlọ àwọn adúláwọ̀ àti àwọn obìnrin nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí ló ṣòfò, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀jẹ̀ ló ti dà sílẹ̀ kí ẹ̀tọ́ ìdìbò tó sún kan àwọn obìnrin àti àwọn adúláwọ̀ ní Orílẹ̀èdè Amẹrika. Pangram Yorùbá Tí a bá wí pé “Ayára kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ aláwọ̀ èèpẹ̀ fò gborí ọ̀lẹ ajá kọjá”. Kíni ìtumọ̀ èyí? Kò ní ìtumọ̀ kankan pàtó ní èdè Yorùbá. Ṣùgbọ́n ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, gbólóhùn pàtàkì gbáà ni. “The quick brown fox jumps over the lazy dog” ni ó túmọ̀ sí ní Gẹ̀ẹ́sì. Ìdí tí gbólóhùn yìí fi ṣe pàtàkì ni pé ó jẹ́ nkan tí àwọn onígẹ̀ẹ́sì npè ní “Pangram”. Ìyẹn ni pé nínú gbólóhùn kan ṣoṣo yìí, gbogbo álúfábẹ́ẹ̀tì Gẹ̀ẹ́sì ló péjọ síbẹ̀ láti A dé Z. Kò sí irúfẹ́ gbólóhùn yí tó jẹ́ mímọ̀ pàtó ní èdè Yorùbá tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá gbólóhùn ọ̀hún ti balẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà, Moses Mabayọjẹ ló ṣe àgbékalẹ̀ gbólóhùn yìí sí orí ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́ tí nbẹ lórí Ayélukára tí wọ́n npè ní Wikipedia. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn àgbàlagbà Yorùbá, òwe àgbà kan ni alàgbà yìí gbéyọ tí wọ́n sì kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tí ó fi kó gbogbo álúfábẹ́ẹ̀tì Yorùbá mọ́ra, ṣùgbọ́n tí ìtumọ̀ rẹ̀ kò yí padà rárá. Ṣé Yoòbá ti wí tẹ́lẹ̀ pé òwe lẹṣin ọ̀rọ̀. Gbólóhùn náà ni : “Ìwọ̀fà ń yọ̀ séji tó gbojúmọ́, ó hàn pákànpọ̀ gan-an niṣẹ́ rẹ̀ bó dọ̀la”. Gbogbo álúfábẹ́ẹ̀tì Yorùbá mẹ́dẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni wọ́n péjọ sínú gbólóhùn yìí. Àb'ẹ́ẹ̀ rínkan? Mo kí Alàgbà Mábayọ̀jẹ́ fún iṣẹ́ ọpọlọ tí wọ́n ṣe lórí ọ̀rọ̀ yí. Ẹlẹ́dàá ò ní jẹ́ kí àgbà àti ọ̀jọ̀gbọ́n ó tán nílùú o. Já ìtànná tó ntàn Àṣé ọ̀rọ̀ pàtàkì ni orin òwe yìí ńbáwa sọ nígbà kékeré. Ó máa ńmú inú mi dùn tí mo bá ńrántí ẹ̀. Já ìtànná tó ntàn Tó tutù tó sì dára Má dǔró dọjọ́ ọ̀la Àkókò ńsúré tete J.F Odunjo Iléyá ti dé “♪…Iléya ti dé! Iléya ti dé! Iléya ti dé o, barika de Sallah ..♪” Orin kan tí gbogbo àwọn ọmọdé máa nkọ ní ìlú wa nígbàtí mo wà ní kékeré nìyẹn. Tí ọdún iléya bá ti dé, gbogbo àwọn ọmọdé yálà Mùsùlùmí tàbí Onígbàgbọ́ Kìrìstẹ́nì ni, wọ́n a máa kọrin bẹ́ẹ̀. Ní gbogbo àgbáyé, níbi tí a ti lè rí àwọn Mùsùlùmí àti Kìrìstẹ́nì tí wọ́n ngbé pọ̀ ní ìlú kannáà, kòsí ibi tí ìrẹ́pọ̀ wà tó ti ilẹ̀ Yorùbá! Ìdí abájọ ni pé ní ìdílé kan, a lè rí ẹnìkan tó jẹ́ Mùsùlùmí, kí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò onítọ̀hún jẹ́ Kìrìstẹ́nì. A rí mọ̀lẹ́bí ẹlẹ́sìn Ìgbàgbọ́ àti Mùsùlùmí ní agbolé kannáà nítorí wọ́n a máa fẹ́ arawọn láì sí ìkórira kankan. Àpẹrẹ rere ni èyí jẹ́ fún gbogbo àgbáyé. Pàápàá jùlọ fún àwọn ìlú tí àwọn ẹlẹ́sìn méjéèjì ti dojú ìjà ko arawọn. Àti fún àwọn aríwá orílẹ̀ Nàìjíríà lókè Ọya lọ́hùn-ún. Ní ìlú tiwa ṣá o, àti Kìrìstẹ́nì o, àti Mùsùlùmí o, àti Abọ̀ìṣà o, àjọjẹ lẹran Iléyá! Ìgbà Ìwọ́wé Ní ìhà àríwá aiyé, ìgbà ìwọ́wé ni a wà báyìí. Àsìkò yí ni ìgbà ooru nré kọjá lọ, tí ìgbà òtútù nbọ̀ lọ́nà. Ni dédé oṣù kéèjé ọdún ni àsìkò yìí bẹ̀rẹ̀. Ìgbà yìí ṣe pàtàkì fún àwọn àgbẹ̀ nítorí àsìkò ìkórè ló jẹ́. Onírúirú èso àti nkan ọ̀gbìn ni wọ́n nta tí wọ́n npọ́n tí wọ́n sì nrẹ̀ ní àsìkò yìí. Gẹ́gẹ́ bí àṣà wọ́n ní ilẹ̀ Yúróòpù, àwọn ìlú kọ̀ọ̀kan ní àjọ̀dún àti ìdúpẹ́ tí wọ́n máa nṣe ní àsìkò yìí. Àwọn àṣà wọ̀nyí náà ló tàn dé ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Gẹ́gẹ́ bí ayàwòrán, mo fẹ́ràn àsìkò yìí lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí bí àwọn ewé orí igi ṣe máa npa àwọ̀ dà. Gbogbo ibi tí igi bá pọ̀ sí a wá dùn ún wò gidi-gaan nítorí àwọn ewé àti èso aláràbarà t'ọ́n nbẹ lórí wọn. Tí atẹ́gùn bá fẹ́, àwọn ewé wọ̀nyí á wá máa wọ́, wọ́n á máa rẹ̀ sílẹ̀ bí ẹni pé ó nrọ̀jò ewé ni. Gbogbo àdúgbò ọ̀hún á wá rẹwà lójú dáadáa. Àmọ́ ṣá, ènìyàn ò lè ṣàì ronú oun tí nbọ̀ lọ́nà níoripé afẹ́fẹ́ tútù ní í fẹ́. Láìpẹ́ láìjìnnà, Ọ̀gìnìntìn nbọ̀. Yorùbá kíkọ pẹ̀lú àmì Orísìírísìí ọ̀nà ló ti wà fún kíkọ èdè Yorùbá sílẹ̀ pẹ̀lú àmì. Mo gbìyànjú láti ṣe àlàyé àwọn kan láti dáhùn ìbéèrè tí ẹnìkan bi mí lórí Twitter. Tí ẹ bá ní ìbéèrè míràn, ẹ má sàìfiránṣẹ́ sí mi ní Ọgbà ìfọ̀kànbalẹ̀ Àláfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ṣe pàtàkìfún ìlera wa. Bíótilẹ̀jẹ́pé iṣẹ́ àti àwọn ojúṣe wa ò kí nṣábàá gbàwá láàyè láti dá àkókò ìsinmi sí lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ó ṣe kókó kí a gbìyànjú ẹ̀. Ní tèmi o, mo máa nlọ sínú ọgbà kan nítòsí láti gba ìsinmi. Ọgbà yìí rẹwà púpọ̀ ó sì máa nṣábàá dákẹ́ rọ́rọ́. Ó ní adágún omi kan tí àwọn ẹja onírúirú wà, tí àwọn apẹjagbafẹ́ sì máa nwa jòkó sí etí ẹ̀. Mo má nlo ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sí wákàtí kan níbẹ̀. Àláfíà gbáà ni èyí jẹ́ fún mi. Ó sì tún fún mi ní àsìkò láti ronú jinlẹ̀ dáadáa. Mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ṣókí nínú móhùnmáwòrán tó wà lókè àkọslẹ̀ yìí. Ẹkú ayájọ́ òmìnira Nàìjíríà Ọjọ́ òní ló di ọdún méjìléláàádọ́ta báyìí tí Orílẹ̀ Nàìjíríà gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba amúnisìn ti ọba àwọn Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn ni wọ́n kó ilẹ̀ Yorùbá pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà míràn bíi àwọn Igbo àti Hausa sí orílẹ̀ kannáà, tí wọ́n sì sọ wá lórúkọ ��Nigeria”. Bíótilẹ̀jẹ́pé ànfàní mélòókan wà nínú bí wọ́n ṣe kó wa pọ̀ yìí, àlébù tí nbẹ́ níbẹ̀ kò níye. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ọjọ́ mìíì nìyẹn jẹ́. Àkọsílẹ̀ tòní, ìkíni ló jẹ́. Ìkíni gbogbo ọmọ Nàìjíríà jákè-jádò nílé lóko lódò lẹ́hìn odi àti níbikíbi tó wù kí ẹ wà. Ẹkú ayájọ́ òmìnira orílẹ wa o. Ẹkú ọjọ́dọ́gba àná o Yoòbá ní “Aiyé nyí lọ biri-biri bí òkúta”. Àṣé ìtunmọ̀ nbẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí ju bí a ṣe rò lọ. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀jìnlẹ̀ ti fi yé wa pé ọ̀bìrìkìtì ni ilé-aiyé nṣe, kìí ṣe pẹlẹbẹ. Bí ilé-aiyé ṣe tóbi tó, àti bí àwa ọmọ ènìà ṣe kéré síi to, ló fi dà bẹ́ẹ̀ lójú tiwa. Àti pé ilé-aiyé yìí ò dúró lójú kan rárá. Nṣe ló nyí birir bí òkòtó. Ó sì tún npòòyì yí òòrùn po. Ìyíbiri ẹyo kan ló nfúnwa ni ẹyọ ọjọ́ kan. Nítorí pé ihà ilé-aiyé kan ló kojú sóòrùn lẹ́ẹ̀kannáà, tí ìdàkejì á sì kọjú sí òkùnkùn òfurufú, ìmọ́lẹ̀ òòrùn yìí ni a npè ní ojúmọ, tí òkùnkùn ṣì njẹ́ àsìkò alẹ́ àti òru. Wákàtí mẹ́rìnlélógún ni ilé-aiyé fi nyí biri lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, èyí tí nṣe ọjọ́ kan. Nítorí ilé-aiyé dàbí ọ̀bìrìkì, o yẹ́ kí iye wákàtí tí ihà a rẹ̀ kọ̀ọ̀kan fi kọjú sóòrùn jẹ́ méjìlá, kó sì kọ́ju sókùnkùn fú iye wákàtí kannáà. 12 + 12 = 24. Ìyẹn ni pé kí ojúmọ́ àti ilẹ̀ṣú jẹ́ dọ́gba-dọ́gba. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ní ihà àríwá ilé-aiyé àti ihà gùsù aiyé pẹ̀lú, ọjọ́ ò dọ́gba rara. Ìdí èyí ni pé ilé-aiyé rọra fì sí egbẹ́ kan. A jẹ́ pé bí ó ṣe nyí òòrùn po, nígbà míràn á kọ́ orí (àríwá) sóòrùn, nígbàmíì á kọ ìdí (gusu) síi. Ìgbà tí ilé-aiyé kórí sí òòrùn yìí ni a máa nrí ìgbà ooru. Ìgbà tó kọ̀dí sí òòrùn ni ìgbà òtútù ní ìhà àríwá ilé-aiyé. Ààrin ìgbà méjéèjì wọ̀nyí ni ìgbà ìrúwé tí ìgbà òtútù nparadà di ìgbà ooru, àti ìgbà ìwọ́wé tí ìgbà ooru nparadà di ìgbà òtútù. nkan bíì ọsù mẹ́ta-mẹ́ta ni ìgbà kọ̀ọ̀kan ngbà, tí ìgbà mẹ́rẹ̀rin bá kọjá tán ni ó di ọdún kan, tí nṣe oṣù méjìlá. 3 x 4 = 12. (Gbogbo nkan to bá nṣẹlẹ̀ ní àríwá ilé-aiyé, ìdàkejì rẹ̀ ló ma nṣẹlẹ̀ ní gusu. Kí ng fi gé àkọsílẹ̀ yìí kúrú, ti àríwá nìkan ni mo mẹ́nu bà.) Ìyẹn ló fàá tó fi jẹ́ pé nígbà ooru, ọjúmọ́ máa ngùn ju ilẹ̀ṣú lọ. Òòrùn á tètè là nídàájí, á sì pẹ́ wọ̀. Ìdàkejì rẹ̀ sì làá rí nígbà ọ̀gìnìntìn tí nṣe ìgbà òtútù. Bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe nlọ ni ojúmọ àti ilẹ̀ṣú a máa gba ìsẹ́jù méjì-méjì lọ́wọ́ arawọn, títí tí wọ́n a fi dọ́gba ní wákàtí 12 sí 12. Ẹ̀ẹ̀mejì péré ni ọjọ́ ndọ́ga báyìí lọ́dún. Ọ̀kan bọ́sí ìgbà ìrúwé tí ojúmọ́ ngùn síi. Ìkejì bọ́sí ìgbà ìwọ́wé tí ojúmọ́ nkuru síi. Ní ọjọ́ méjéèjì wọ̀nyí ni ilé-aiyé kọ ẹ̀gbẹ́ sí òòrùn. Tí àríwá àti gùsù aiyé kọ ara sóòrùn ní dọ́gba-dọ́gba, tí wakàtí ìmọ́lẹ̀ òòrùn àti òkùnkùn ṣì jẹ́ méjìlá gérégé. Àwọn ọjọ́ ọṣù tí ọjọ́ ndọ́gba báyìí a máa fi ọjọ́ kan sí méjì yàtọ̀ lọ́dọọdún. Lọ́dúnnìí, ọjọ́dọ́gba ìgbà irúwé bọ́sí 20 Ẹrẹ́nà (oṣù kẹta). Wọ́n fi yé wa pé ó yára dé lọ́dúnìí. Pé láti ọdún 1896 ló ti tètè dé báyìí gbẹ̀hìn. Ọjọ́dọ́gba ìgbà ìwọ́wé bọ́sí 21 Ọ̀wẹ́wẹ́ (ọsù kẹsàn-án), tí nṣe àná! Nítorí pé ilẹ̀ Yorùbá súnmọ́ ààrin ọ̀bìrìkìtì aiyé, ènìà ò lè rí iyàtọ̀ púpọ̀ láàrin ojúmọ́ àti ilẹ̀ṣú rárá, Bíótilẹ̀jẹ́pé ìyàtọ̀ isẹ́jú mélòókan máa nwà. Àmọ́ fún àwọn tó ngbé ní ìhà aríwá tàbí gùsù àgbálá-aiyé, ìyàtọ̀ hàn gedegbe. Gẹ́gẹ́ bí àṣà wa ní ilẹ̀ Yorùbá, a máa nkírawa gẹ́gẹ́ bí ojú ọjọ́ ti rí ni. A jẹ́ pé mo kí gbogbo yín ẹkú ọjọ́dọ́gba àná o! Roomba amáíyérọrùn Ìmọ́tótó borí ààrùn mọ́lẹ̀. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ gidi ni. Láíyé àtijọ́, ṣèbí ọwọ̀ ìgbálẹ̀ tí wọ́n fi màrìwò ọ̀pẹ ṣe la fi ngbálẹ̀. Òun náà la fi ngbọn jànkáríwọ̀ kúro lára ògiri inú ilé. Láíyé àtijọ́ tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbí ni wọ́n ngbé pọ̀ nínu agbolé kannáà, àjọ́gbá ni ilẹ̀, àjọṣe ni iṣẹ́. Tí àwọn púpọ̀ bá pé jọ gbálẹ̀, kíá kiá ni wọ́n ngbálẹ̀ tán. Iṣẹ́ náà a wá dàbí ti ikán tọ́n parapọ̀ tọ́n mọ'lé. Àjọṣe ló rọrùn. Láíyé òde òní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ndá gbé, tàbí kí wọ́n pé ẹyọ méjì péré nínú ilé kan. Pàápàá ní àwọn ìdílé alákọ̀wé. Aiyé daiyé òyìnbó 🙂 Nítorí ìgbésí aiyé alákọ̀wé yàtọ̀ sí ti àtijọ́, àti pé jíjí tí wọ́n njí lọ ibiṣẹ́ lójoojúmọ́ ò fààyè sílẹ̀ fún ilẹ̀ gbígbá. Àmọ́ o, òyìnbó tó saiyé dẹ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rọ-ìgbálẹ̀ níjọ́sí ti tún gbé tuntun dé o. Roomba ni wọ́n npèé. Yàtọ̀ sí ẹ̀rọ-ìgbálẹ̀ alátìká, Roomba yìí máa nfúnrarẹ̀ gbálẹ̀ láì sí ìrànlọ́wọ́ enìkankan ni. Nígbà tí èèyàn bá kọ́kọ́ tàn án, Roomba á fúnni ní ànfàní àti ṣe ẹ̀tò àsìkò tí èèyàn fẹ́ kó gbálẹ̀ lójúmọ́. Èèyàn lè sọ ọjọ́ ọ̀sẹ̀ wo ni kó gbálẹ̀, ati ní wákàtí wo. Tí àsìkò bá tó Roomba a tají á bẹ̀rẹ̀ sí í gbálẹ̀. Tó bá sì ṣe tán á padà sí ibi tí ó nsùn sí. Ó ní àpọ̀ nínú tó nfa gbogbo ìdọ̀tí sí. Èèyàn ní láti da ìdọ̀tí inú ẹ̀ nù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tó bá ti kún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó nlo Roomba yìí a máa fi àkókò ìgbálẹ̀ sí ìgbà tí wọn ò bá sí n'lé. Nígbà tí wọ́n bá wọlé dé, ilẹ̀ á ti mọ́n tóní-tóní. Roomba náà a ti dákẹ́ rọ́rọ́ sí ẹ̀bá ibi tí wọ́n gbé e sí. Njẹ́ Alákọ̀wé ò ní wá ọ̀nà ra ọ̀kan báyìí? Àb'bẹ́ẹ̀ ríi pé ìrọ̀rùn gbáà ni? Ó kàn jẹ́ pé ó fẹ́ gbówó lérí díẹ̀. EarPod olówó pọ́ọ́kú gbòde Mo ti jáwọ́ lápọ̀n tí ò yọ̀ wàyí, mo ti gbómi ilá kaná. Ilá ọ̀hún sì yọ̀ bọ̀lọ̀-bọ̀lọ̀ gidi. Ẹwo ni ká má tíì lo nkan fún oṣù kan sí méjì, kóti tètè bàjẹ́? Kiní agbórinsétí mà ló gbé ìṣe rẹ̀ dé o. Sony MDREX50LPW tí mo rà níjọ̀ọ́sí ló mà ti bàjẹ́ o. Mo tìí bọ'tí pé kí ng máa gbádùn orin lọ ni apá ọ̀tún rẹ̀ bá ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe dákú-dájí. Ìgbà tó yá ó kúkú wá dákẹ́ pátápátá. Ówá jẹ́ etí kan péré ló ngbé ohùn sí. Toò, kò kúkú yẹ kó yàmí lẹ́nu púpọ̀. Owó ránpẹ́ ni mo san nígbà tí mo ràá. Wọ́n dínwó rẹ̀ kù níbi tí mo ti ràá ni. Àṣé wọ́n fẹ́ tètè ta gbogbo ẹ̀ kúrò lórí igbá ni. Kò sì sọ́nà àti dá a padà mọ́ báyìí. Èmi ò lè ṣe kí ng má máa gbọ́ àgbọ́rìn o. Orin ni o, ìròhìn ní o tàbí ìwé àfetígbọ́, gbogbo ìgbà ni èmi máa ngbọ́ nkan ní tèmi. Nítorínáà, mo yára sáré lọ sí ilé-ìtajà Apple kan tí nbẹ láàrin ìlú. Mo ra agbórisétí tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde tí wọ́n npè ní EarPod. EarPod yìí, iPod àti iPone ni wọ́n ṣe é fún. A máa gbóhùn sétí, a sì máa gba ohùn lẹ́nù. Ìyẹn ni pé èèyàn lè fi báni sọ̀rọ̀ láì gbé ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ gan-gan sétí. Kódà èèyàn lè lòó fi darí iPhone/iPod – fi jẹ́ ìpè ago, fi yín orin sókè tàbí sílè, fi yan orin míràn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́ nkan tó ṣe pàtàkì jùlọ nípa rẹ̀ ni pé Apple fúnni ní ìdánilójú pé ti EarPod yìí bá bàjẹ́ láàrin ọdún kan, àwọn ó fúnni ní òmíran tuntun, tí àwọn ò bá lè tún un ṣe. Ilé-Iṣẹ́ yìí sì ni àdéhùn tó ṣe é gbójúlé, tó sì fúnni ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Àti pé dídárasí ati wíwuyìsí EarPod olówó pọ́ọ́kú yìí, bíi ti olówó iyebíye ni. Toò, kí ng wá gbé orin Aṣa kan síi ojàre. Arúgbó atọrọjẹ òyìnbó bọ̀ ó pòwe Arúgbó òyìnbó bọ̀ ó pòwe. Ó ní “bí iṣu ẹni bá ta àá fọwọ́ bòójẹ ni”! Èèbó káàbọ̀. Ọ̀rọ̀ kànkà yí wáíyé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tí èmi àti ọ̀rẹ́ mi kan fẹ́ pàdé láàrin ìlú. Ọ̀rẹ́ mi náà ló pẹ́ díẹ̀ kó tó dé ti mo fi lọ́ dúró dèé ní Starbucks kan tí nbẹ lẹ́bàá ibi tí a fìpàdé sí. Nínú gbogbo onírúirú nkan mímu tí wọ́n ntà níbẹ̀, frapuccinno ni mo yàn nítorí ooru mú díẹ̀ lọ́jọ́ náà. Frapuccinno yìí, omi-dídì ni wọ́n fi nṣe é. Wọ́n á lọ̀ọ́ kúnná, wọ́n á wá da Kọfí lùú, wọ́n a wá pòó pọ̀ dáadáa nínu ẹ̀rọ ọlọ. Gbogbo ẹ̀ á wá tutù nini. Ìtura gbáà ló jẹ́ nígbà ooru. Ní ìta gbangba ibi wọ́n to àga sí fún àwa oníbàárà wọn ni mo fìkàlẹ̀ lé o. Mo ti agbórinsétí bọ̀ ẹtí, mo yín ọrin aládùn síi lóri iPhone mi, kí afẹ́ bẹ̀rẹ̀ ní kẹlẹwu. Atẹ́gùn àlàáfíà kan náà bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́. Mo bá fẹ̀ pẹrẹgẹdẹ sórí àga mo fẹ̀hìntì dáadáa. Mo kọ̀wé ranṣẹ́ sí ọrẹ́ mi sórí alágbèéká rẹ̀ pé kó wá bámi níbẹ̀ tó bá dé. Bí mo ṣe fẹ́ máà bá ìgbádùn mi lọ ni mo fura pé ẹnìkan nbẹ lẹ́hìn mi. Wéré ni mo bá bojú wẹ̀hìn. Mo rí ìyá arúgbó òyìnbó kan tó nsọ̀rọ̀ kan sí mi, ṣùgbọ́n tí ng kò gbọ́ nkan tó nsọ nítorí kiní orin tí mo tì bọ'tí. Mo bá yọ ọ́ létí kí ng fi lè gbọ́'hun tí arúgbó nwí. Àṣé ìyá yìí ntọọrọ owó ni. Ó ní kí ng jọ̀ọ́ ṣe ìrànlọ́wọ́ fún òun kí òun lè rí oúnjẹ jẹ. Ah! Àánú arúgbó náà ṣe mí púpọ̀. Iye owó tó tọọrọ kò tó ìdajì owo frapuccinno tí mo gbé síwájú mi. Mo bá tọwọ́ b'àpò mo kó gbogbo owó tí nbẹ níbẹ̀ fún arúgbó yìí. Kìí ṣe owó bàbàrà lọ títí o, àmọ́ ó jọ̀ọ́ lójú púpọ̀ púpọ̀. Ìyá arúgbó òyìnbó bá dúpẹ́ dúpẹ́. Ó wí pé ó ya òun lẹ́nu gidi pé mo fún òun lówó. Àti pé ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Èmi sọ fún un pé kò tọ́pẹ́ rárá. Pé kó yáa sáré lọ wá nkan jẹ, kí òyì má kọ́ọ kó má dàákú síwa lọ́rùn o. Ìgbà náà ló bá nawọ́ sí àwọn kan tọ́n jòkó lókèrè. Ó wípé ọ̀dọ̀ wọn lòun ti kọ́kọ́ tọọrọ owó, ṣùgbọ́n wọn kò fún òun ní nkankan rara. Kódà wọ́n lé òun dànù ni. Àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan ni. Wọ́n n fi gbogbo ẹnu sọ̀rọ̀. Wọn kó owó iyebíye kalẹ̀ wọ́n npín-in láàrin arawọn. Gbogbo nkan tí wọ́n nsọ ni gbogbo aráyé ngbọ́ pátápátá. Ó dàbí pé iṣẹ́ òwò kan tí wọn sẹ ni wọ́n ti jèrè rẹpẹtẹ, ti wọ́n fi nyọ̀ bẹ́ẹ̀. Àkókò yìí ni àgbàlagbà òyìnbó bá mín kànlẹ̀, ó sọ̀rọ̀ àgbà. Ó wípé ọjọ́ ti pẹ́ tí òun ti wà ládùúgbò náà. Òun sì mọ bí nkan ṣe rí. Ó wípé àwọn jàgùdà pọ̀ láàrin yẹn tí wọ́n wá nkan tí wọ́n máa jígbé. Pé kò ní yà òun lẹ́nu tí àwọn jàgùdà olè bá tẹ̀lé àwọn ọkùnrin náà láti jàwọ́n lólè, tí wọ́n á sì gba gbogbo owó ọwọ́ wọn. Ó bá tún dúpẹ́ lọ́wọ́ mi lẹ́ẹ̀kan síi, kó tó máa rọra rìn lọ.   Yakubu Adesokan ṣe oríire Ìwúrí àti àyọ̀ nlá ni fún gbogbo ọmọ Yorùbá àti gbogbo Nàìjíríà lápapọ̀ lónìí! Ọmọ ìyá wa Yakubu Adesokan ló mà fúnwa láyọ̀ o. Adesokan jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn eléré ìdárayá wa tí Nàìjíríà rán lọ́ ibi ìdíje Paralymics tó nlọ lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí ní ìlú London. Arọ ni alákùnrin yìí jẹ́, iye ọjọ́ orí i rẹ̀ sì nṣe mẹ́tàlélọ́gbọ̀n. Ẹré tirẹ̀ jẹ́ ìdíje ìgbẹ́rùwíwo sókè. Lásán kọ́ ni pé alákùnrin yìí gbé ipò kíní, ìyẹn ni pé ó gba wúrà, ìwọ̀n ẹrù tó rí gbé sókè, kò tíì sí ẹni ẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ kankan tó gbé ìwọ̀n wíwo báyìí rí! Ìyẹn ni pé láti ìgbà tí ìdíje yìí ti bẹ̀rẹ̀, Yakubu ni ipò kíní pátápátá. Àb'ẹ́ẹ̀ rí nkan? Ọjọ́ ìkíní rèé o, a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. 'Ó tún kù!' ni ìbọn nró! Àjọ̀dún Notting Hill Ijó rẹpẹtẹ. Ìlù rẹpẹtẹ. Orin rẹpẹtẹ. Àríyá rẹpẹtẹ ló ṣẹlẹ̀ ní àdúgbò ìwọ̀-oòrùn London. Gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ lọ́dọọdún, àjọ̀dún Notting Hill ló gbọ̀de lọ́jọ́ Àìkú àti ọjọ́ Ajé tó kọjá. Ní ọdún 1965 ní àjọ̀dún yìí kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Àwọn tí wọ́n wá láti àwọn erékùṣù Caribbean (tí wọ́n jẹ́ ìran adúláwọ̀ tí àwọn òyìnbó kó lọ sóko ẹrú láíyé àtijọ́) ní wọ́n dáa sílẹ̀. Pàápàá jùlọ àwọn ará ìlú Trinidad. Lóde òní wàyí, ó ti di ayẹyẹ gbogbo gbòò, gbogbo ẹ̀yà, gbogbo ìran ni. Iyé ènìà tó pé jọ fún ayẹyẹ náà lé ní 1,000,000! Kò tún sí ibòmíràn ní gbogbo àgbáyé tí èro pọ̀ báyìí fún ayẹyẹ àjọ̀dún ti gbangba ojú títì, àfi ní ìlú Rio de Janeiro ni orílẹ̀ Brasil. Iṣẹ́ nlá ni fún àwọn ọlọ́pàá nítorí ojúṣe wọn ni láti pèsè àbò àti ìdarí èrò nlá yìí. Nítorí èyí, àwọn ọlọ́pàá a máà gbáradì fún oṣù mélòó kan kí ayẹyẹ náà tó wáyé. Pàápàá ní ọdúnnìí tó tún bọ́ sí àrin ìdíje nlá méjì tí ìlú London gbà lálejò. Bótilẹ̀jẹ́pé ọ̀nà kannáà ni wọ́n ngbà lọ́dọọdún, àwọn olùdarí ètò ayẹyẹ a máa gbìmọ̀pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá láti ríi dájúdájú pé kò sí ewu kankan lọ́nà tí gbogbo ètò náà á tọ̀ kọjá. Àti pé nítorí púpọ̀ nínú awọ̀n ọ̀nà wọ̀nyí gba iwajú ilé àwọn ènìà kọká. Àwọn ọlọ́pàá a sì máa gbe igi dínà tàbí kí wọ́n o kan ọgbà dí àwọn ọ̀nà kékèké kan tó bá gba àrin'lé ẹlòmíràn kọjá. Gbogbo ẹ̀ náà láti dáàbò bo nkan ìn�� àti dúkìá àwọn ará àdúgbò ibẹ̀ ni. Àwọn ọkọ̀ agbérò nlá nlá ni wọ́n máa nkó àwọn ẹ̀rọ gboùngboùn sí tí wọ́n a máa fi gbóùn àti orín sáfẹ́fẹ́ fún ìgbádùn gbogbo èrò. Àwọn ọmọ oníjó a sì máa jó tẹ̀lé àwọn ọkọ̀ nla wọ̀nyí títí wọ́n á fi tọ ọ̀nà já. Àwọn ọmọ oníjó wọ̀nyí, púpọ̀ nínú wọn a máa wọ aṣọ bí eléégún aláràbarà. Nítorí àwọn ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ní wọ́n njó tẹ̀lé ọkọ̀ tiwọn, wọn a máa mú u bí ìdíje ni. Ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan a fẹ́ dárà jú àwọn ìyókù lọ. Wọ́n a tún máa to àwọn ẹ̀rọ gboùngboùn agbóùnsáfẹ́fẹ́ sí àwọn òpópónà kàn tí àwọn òṣèré á máa lú onírúirú àwo olórin fún ìgbádùn àwọn èro tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ ọ wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ìsọ̀ olóúnjẹ́ onikanòjọ̀kan náà máa nwà káàkiri fún àwọn èrò láti ra óújẹ jẹ. Fún ọjọ́ méjì gbáko ni àríyá yìí lọ. Bótilẹ̀jẹ́pé àwọn màndààrú àti jàgùdà kọ̀ọ̀kan ò lè sàì wà níbẹ̀, àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ a máa mu igbó níbẹ̀, gbogbo ẹ̀ a máa sábàá lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ ni. Ìdíje àwọn àkàndá àti abarapa ẹ̀dá Ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́hìn tí wọ́n parí Ìdíje London 2012, abala kejì tí wọ́n npè ní Paralimpics á bẹ̀rẹ̀. Paralimpics yìí jẹ́ Ìdíje àwọn àkàndá àti abarapa ẹ̀dá. Ìyẹn ni pé gbogbo àwọn eléré ìdárayá tí wọ́n máa kópa nínú ìdíje náà a jẹ́ àkàndá àti abarapa ẹ̀dá bákan. Òmíràn nínú wọn á ní ẹsè eyọ ìkan péré. Ẹlòmíràn lè jẹ́ afọ́jú, arọ, alápá'kan, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Computer kìí ṣẹ Ayárabíàṣá Ó dáa ó dáa! Mo mọ̀ pé ẹ̀rọ ayárabíàṣá lorúkọ tí computer njẹ́ ní èdè Yorùbá. Ng kò jiyàn rẹ̀ rárá o. Dájúdájú gbogbo wa la ti gbà pé orúkọ rẹ̀ nìyen. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá fojú inú wòó, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe ní alẹ́ ọjọ́ kan, ẹ ó ríi pé orúkọ yìí kù díẹ̀ káà tó! Ní alẹ́ ọjọ́ tí mo nsọ yìí, mo tan ẹ̀rọ ayárabíàṣá mi pé kín sáré ṣiṣẹ́ kan kíakiá kí ng tó lọ sùn. Títàn tí mo tàn án tán, lóbá dí kùùrùrù, ó di kẹẹrẹrẹ. Bí ó ti nsún kẹrẹ ni ó nfà kẹrẹ. Nkan tí kò gbà ju ìsẹ́jú kan lọ tẹ́lẹ̀, ó di oun tí a nfi ìsẹ́jú mẹ́rin ṣe. Gbogbo ẹ̀ wá nfẹsẹ̀ falẹ̀ bí ìjàpá. Ẹ̀rọ wá di ẹ̀rọ àfìdíwọ́bíìgbín! Àb’ẹ́ẹ̀ rí nkan? njẹ́ orúkọ yìí péyé mọ́n? Ótì o, èmi ò rò bẹ́ẹ̀ rara. Nkan tó nṣẹlẹ̀ nipé lẹ́hìn bíi ọdún méjì láti ìgbà tí ènìà bá kọ́kọ́ ra ẹ̀rọ ní títun, ẹ̀rọ náà á bẹ̀rẹ̀ sí ígbọ́. Àwọn nkan inú ẹ̀rọ tí wọ́n nmú u ṣiṣẹ́ náà a máa gbó pẹ̀lú. Àmọ́ pàápàá jùlọ, nkan tó fàá nipé bí àsìkò àti ìgbà ṣe nlọ síwájú ni iṣẹ́ tí a nfún ẹ̀rọ yìí ṣe nsòro síi tí ó sì nwúwo síi. Agbára ẹ̀rọ á sì máà dínkù síi titi agbára rẹ̀ ò fi ní ká iṣẹ́ tí a nfi ṣe dáadáa mọ́. A jẹ́ pé fún bíi ọdún kan péré náà ni ẹ̀rọ yìí fi nyára bí àṣá. Ọrúkọ wo láà bá wá sọ Computer ní Yorùbá? Wọ́n ní ilé làá kọ́kọ́ wò. Óyá ẹ jẹ́ ká gbé e yẹ̀wò. T’ọ̀wọ̀ t’ọ̀wọ̀ ni mo fi sọ̀rọ̀ yí o, ṣùgbọ́n èro mi ni pé àwọn tí wọ́n sọ computer ní ayárabíàṣá, ìtumọ̀ "Computer" àti iṣẹ́ tí ó nṣe kò yé wọn dáadáa ni. Láti èdè Latin ni "Computer" ti jáde gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀. "Computare" ni ọ̀rọ̀ yí gan-gan ó sì túmọ si "kíkà" tàbí "sísírò" ní Yorùbá. Ní nkan bíi 1940 sí 1945 ni wọ́n ṣẹ̀dá Computer àkọ́kọ́ ní ìlẹ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Iṣẹ́ tí ó kọ́kọ́ nṣe nígbà náà ni ìsirò. Àwọn ìsirò ònkà nlá-nlá tí ó sòro púpọ̀ púpọ̀ fún ọmọ ènìà láti ṣe ni ẹ̀rọ yìí nṣe ní kíákíá láì tàsé. Ìgbà tí ìlọsíwájú dé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí máa wá ọ̀nà fi ẹ̀rọ yìí ṣe onírúirú iṣẹ́ míràn bíi ìwé kíkọ, kíkà àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ. L’áíyé òde òní, ìmọ̀-ẹ̀rọ yìí ti gbòòrò gidigidi, ó sì ti dàgbà sókè dé ibi pé kò fẹ́ẹ másìí nkan ẹ̀rọ ìgbàlódé kankan tí kò ní ẹ̀rọ yìí nínú. Àti pé kò fẹ́ẹ másìí iṣẹ́ tí kò lè ṣe. Ó nṣiṣẹ́ amóhùmáwòrán, ó nṣiṣẹ́ asọ̀rọ̀mágbèsì. Kódà aiyé tó d’aiyé aiyélujára yìí, ó tún nṣiṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. Kí laà bá wá pe Computer yìí ní Yorùbá tí kò bá tọ̀nà, tí kò bá bá ìtunmọ̀ mu rẹ́gí-rẹ́gí? Ẹ̀rọ Ìsirò!! Elizabeth ti lo ọgọ́ta ọdún lórí oyè Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kaàrún ọdú un 1953 ni Elizabeth gorí oyè. Ó wa jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba orílẹ̀èdè UK àti gbogbo àwọn ilú káàkiri àgbáyé tí wọ́n wà lábẹ́ UK nítorí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ló mú wọn sìn. Orílẹ̀èdè Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣùgbọ́n òmìnira dé fún wa ní ọdún un 1960, a sì kúrò lábẹ́ àkóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ní ọjọ́ àyájọ́ ọdúnìí tó pé ọgọ́ta ọdún tí Elizabth gorí oyè, àkànṣe nlá gidi ló jẹ́. Ọjọ́ márùn-ún gbáko ni wọ́n fi ṣe ètò ẹ̀yẹ yìí. Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì dá ọjọ́ Ìṣẹ́gun gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsimin fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ kí wọ́n ó le r’áàyè lọ wòran níbi ayẹyẹ nlá yìí. Ṣé ọjọ́ Ajé kúkú ti jẹ́ ọjọ́ odún kan tẹ́lẹ̀, gbogbo ẹ̀ wá jẹ́ ọjọ́ mẹ́rin – Àbámẹ́ta, Aìkú, Ajé àti Iṣẹ́gun – tí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyàn r’áàyè jáde wòran dáadáa. Kódà ọ̀pọ̀ ló wá láti ọnà jíjìn àti ìdálẹ̀ láti darapọ̀ mọ́n èrò tó wá bọ̀wọ̀ fú ọba yìí. Onírúirú àrà ní wọ́n dá o! Nkan bíì ọgọ́rùn-ún ọpọ́n àti ọkọ̀-ojú-omi ní wọ́n dárà lórí odò Thames fún ọjọ́ méjì. Elizabeth fúnrarẹ̀ wà nínú ọ̀ka nínú àwọn ọkọ̀-ojú-omi yìí. Bíótilẹ̀jẹ́pé òjò nrọ̀, kò dí ayẹyẹ náà lọ́wọ́ rárá. Ní ọjọ́ kẹẹ̀rin ètò yìí, ìyẹn ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Elizabeth ati Àrẹ̀mọ rẹ̀ Charles àti aya rẹ̀, àti àwọn ọmọ àrẹ̀mọ William àti Harry pẹ̀lú ìyàwó William, wọ́n yọjú sí èrò nlá tí wọ́n péjọ sí iwájú àfin rẹ̀. Èyí mú kí wọ́n pariwo kí wọ́n sì pàtẹ́wọ́ kárakára, tí inú u gbogbo wọ́n ndùn gigi nítorípé wọ́n nífẹ̀ ẹ Ọba-bìnrin yìí púpọ̀. Kíákíá wọ́n bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ tí wọ́n máa nkọ fún ọba ní ilẹ̀ náà. Orin náà túmọ̀ pé kí Ọlọ́run dá ọba wọ́n sí o! Bí wọ́n ti nkọ orin yìí tán ni oríṣìíríṣìí ọkọ̀-òfurufú fò kọ̀já lókè e àfin náà. Ọkọ̀-ofurufú ti wọ́n fi njagun ní wọ́n jẹ́. Ọ̀wọ̀ nlá sì ni wọ́n fi bù fún Elizabeth nítoripé ti àtijọ́ ni wọ́n, àwọn èyí tí wọ́n fi jagun nla kan nígbàtí ọba-bìnrin yìí kọ́kọ́ gorí oyè. Èyí tún mú kí gbogbo èrò kígbe kí wọ́n sì pàtẹ́wọ́. Lẹ́hìn èyí ni Elizabeth àti àwọn ẹbí i rẹ̀ padà sínú àfin lọ. Fún wákàtí mélòó kan lẹ́hìn tí Elizabeth wọlé lọ tán, àwọn akọrin tí wọ́n lókìkí tí wọ́n sì gbajúmọ̀ gorí ìtàgé nlá tí wọ́n kọ́ síwájú àfìn ọba, wọ́n sì nfi orin aládùn dá àwọn erò tó péjọ l’árayá. Elizabeth ọba ilẹ̀ Gẹ̀ésì. Ki adé pẹ́ lórí o. Kí bàtà pẹ́ lẹ́sẹ̀ o! Ìbọ̀sẹ̀ Àràmàndà Ẹní bá ga tàbí t’ẹ́sẹ̀ rẹ̀ gùn mà wá dáràn o! Ẹ ní kílódé? Yó dáa fún yín! Ṣébi tí èyàn bá nwá ìbọ̀sẹ̀ tàbí sòkòtò rà, èyí tó bá gùn délẹ̀ tàbí èyí to wọ̀’yàn lẹ́sẹ̀ l’èyàn nwá? Àyàfi tí irúfẹ́ oge kan bá gbòde tójẹ́pé ṣòkòtò-ò-balẹ̀ l’olúwarẹ̀ nkúkú wá ká. Bí bẹ́ẹ̀kọ́, ṣòkòtò gbọdọ̀ gùn délẹ̀ ni. Ó sì yẹ kí ààyè ó gba esè nínú u bàtà pẹ̀lú. Ìwọ̀n tí wọ́n fi nwọnsẹ̀ àwọ́n géndé, láìí ṣe t’ọmọdé, máa nṣábàá bẹ̀rẹ̀ láti 7 dé 12, ìyen fún génde ọkùnrin. Ìgbàmíràn èyàn tún le rí 6 fún àwọn ẹlẹ́sẹ̀ kékeré, tàbí 13 (tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ) fún àwọn ẹlẹ́sẹ̀ gòdògbà. Tí géndé ọkùnrin mẹ́wàá bá wọn ẹsẹ̀, mẹ́jọ tàbí mẹ́sàn-án nínu wọn ni wọ́n á bọ́sí láti 7 dé 10. Nítorí èyí ni àwọn onísọ̀ ibọ̀sẹ̀ dín iye bàtà tó ju 10 lọ kù. Báyìí, wọ́n a le rí bàtà tà dáadáa síi, nítorípé díẹ̀ náà ni iye àwọn oníbàárà wọ́n tí ẹsẹ̀ ẹ wọ́n ju 10 lọ. Nkan tó fa wàhálà fún ẹlẹ́sẹ̀ nlá rèé o! Olúwa rẹ̀ ó wá pàráàró títí yó fi sú u. Tí ẹni ọ̀hún tún bá ṣoríire tó rí ibọ̀sẹ̀ tó bẹ́sẹ̀ ẹ rẹ̀ mu, bàtà nlá yìí ó tún ṣe aláwọ̀ ọ kàlákìnní bákan. Yó wá rí ṣàbìlà-sabila gbúgun-gbùngun bíẹnipé wọn kò f’ẹ̀lẹ̀ ṣẹ̀dá rẹ̀ bí àwọn ìyókù. Gbogbo rẹ̀ ò wá ní bójúmu rárá. Bẹ́ẹ̀náàni fún ṣòkòtò. Àb’ẹ́ẹ̀ rí nkan? Kí ni ẹní bá ga tó sì ní ẹsẹ̀ nlá ó wa ṣe? Tiwantiwa Ẹ̀rọ ìgbàlódé tó gbajú-gbajà tí à mọ̀ sí ‘Aiyélujára’ ti s’aiyédẹ̀rọ̀ báyìí o! Bí ó ti nsọ ẹ̀rọ ayárabíàṣà di amóhùnmáwòrán ni ó nsọ ọ́ di ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì. Kódà, ó kúkú ti sọ ẹrọ̀ asọ̀rọ̀mágbèì di asọ̀rọ̀gbèsì nítorípé ó fún àwọn òlùgbọ́ ètò ní ànfàní àti dásí ètò kí wọ́n sì fèsì sọ́rọ̀. Àb’ẹ́ẹ̀ rí nkan? Ètò ìgbóhùn s’áfẹ́fẹ́ kan ni mo s’àwáàrí ní’jọ́kan. Èdè Yorùbá ni wọ́n fi ngbé ètò náà s’afẹ́fẹ́ fún ìgbádùn àwa elédè káàárọ̀-oòjíire. Tiwantiwa ni wọ́n npe ètò náà gẹ́gẹ́ bíi ètò Yorùbá fún àwa Yorùbá. Amẹ́ríkà ni wọ́n ti ngbé ètò náà si afẹ́fẹ́ àmọ́ bí mo ti wí tẹ́lẹ̀, ànfàní wà láti fetísí ètò náà káàkiri àgbáyé nípasẹ̀ ẹ́ ẹ̀ro ìgbàlódé tó ti mú aiyé lujára bí ajere! Ọjọ́ mẹ́jọ-mẹ́jọ, ìyẹn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, ni ètò náà njáde. Onírúirú abala sì ló wà nínú ètò ọ̀hún. Àwọn àlejò jànkàn-jànkàn a sì máa nwá sórí afẹ́fẹ́, tí wọ́n máa nla àwọn olùgbọ́ l’óye, tí wọ́n sì máa ndáhùn ìbéèrè wọ́n. L’áti ìgbà tí mo ti mọ̀ nípa ètò Tiwantiwa ni ng kò lè ṣàì fetísí i lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀! Ògbóòntarìgì sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni olóòtú ètò náà jẹ́ tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Oyèkúnlé Azeez. Yoòbá ẹnu ọ̀gbẹ́ni náà dùn léti bí orin ewì ni. Alàgbà Mábayọ̀jẹ́ nkọ́? Àwọn ni wọn dúró bí i àgbàlagbà amòyé tí wọ́n máa nsàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ kẹ̀nkẹ̀ ọ̀rọ̀ àgbà. Oníròhìn ná wà tín jẹ́ Sẹ̀san Fáfiólú tí wọ́n ṣe atótó arére sí etí ìgbọ́ wa. Bẹ́ẹ̀náàni Ìyá oge ọlọ́wọ́ ọ síbí ti orúkọ́ wọ́n njẹ́ Tóyìn Sùlàìmán. Ìyá yìí a máa ṣe àlàyé síse oúnjẹ oníkanòjọ̀kan. Ètò yìí jẹ́ nkan ayọ̀ àti ìwúrí fún mi gidi gẹ́gẹ́ bí ọmọ Oòduà. Àdúrà mi ni pé kí Olódùmarè sọ agbára wọ́n di ọ̀tun. Iwáju iwájú ni ọ̀pá ẹ̀bìtì nré sí o! Kíni ìtumọ̀n "SIM Card" l'édè Yorùbá? Ní ọjọ́ mélòókan sẹ́yìn, ẹnìkan bèèrè lórí Twitter pé kí l’àá ṣe npe “SIM Card” ní èdè Yorùbá. Ibérè yìí lo múmi fẹ́ kọ àkọsílẹ̀ ránpẹ́ yìí nítoripé kò ṣeé dáhùn ní gbólóhùn kan lásán. Yorùbá bọ̀ ó pòwe. Ó ní “ẹja l’ẹja íjẹ sanra”. Èyìí ló dífá fún gbogbo èdè pátápátá kárí aiyé! Àlàyé òwe yìí ni pé eja ni èdè. Èdè míràn sì ni èdè nmú mọ́ra kí ó fi gbòòrò síi, ìyẹn nípasẹ̀ èdè-àyálò. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí fún gbogbo èdè l’áíyé. Ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ ṣe àtúpalẹ̀ orúkọ “SIM Card” yìí. SIM Card ni nkan kékeré kan tó wà nínu ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká tó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èròjà ti nmú ẹ̀rọ náa ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ tí SIM Card nṣẹ ni pé òun ló jẹ́ nkan ìdánimọ̀ nínu ẹ̀rọ yìí. SIM Card yìí ni Ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ fi ndá alágbèéká kọ̀ọ̀kan mọn yàtọ̀ sí arawọn. Ike pẹlẹbẹ tí kò tóbi ju bí èkana ọwọ́ lọ ni. Wón sì fi irin ṣe àmì sí ojú ike yìí kan. Inú àmì irin yìí ni wọ́n fi orísìírísìí nkan pamọ́n sí. Ọgbọ́n àti òye ìgbàlódé ni gbogbo èyí jẹ́ tó sì dàbí idán lójú aláìmòye. Orúkọ “SIM Card” yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹyọọ̀kan ṣoṣo o, ọ̀rọ̀ mẹ́rin ni wọ́n mú pọ̀, tí wọ́n tún wá gée kúrú. “Subscriber Identifier Module Card” gangan ni orúkọ rẹ̀ lẹ́kùúnrẹ́rẹ́. SIM jẹ́ lẹ́tà kíní tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mẹ́tẹ̀ta àkọ́kọ́. “Acronym” ni wọ́n npe gígé ọ̀rọ̀ kúrú báyìí ní Gẹ̀ẹ́sì. Ìtunmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yọ kọ̀ọkan rèé Subscriber: Onílò Identity: Ìdánimọ̀ Module: Nkan Card: Ike/Páálí Tí a bá lo irú ìsọnkanlorúkọ yìí, a lè pèé ní “Ike Nkan Ìdánimọ̀ Onílò”, ká tún gée kúrú sí “Ike NIO”. Sùgbọ́n irú orúkọ yìí ò bójúmu, kò sì nítumọ̀ kankan ní Yorùbá. Nkan ìgbàlódé ni SIM Card jẹ́. Ní ọdún 1991 ní orílẹ̀èdè Jamaní ni wọ́n ti ṣẹ̀dá ẹ̀. Ìyẹn bí ogún ọdún àti díẹ̀ sẹ́yìn báyìí. Àwọn tí wọ́n ṣeé náà sì ni wọ́n fún-un lórúkọ l’édè Jamaní àti Gẹ̀ẹ́sì. Èdè wa ò kópa kankan rárá nínú ìṣẹ̀dá rẹ̀. Nítorínáà, a kò ní orúkọ Yorùbá pọnbélé kankan fún-un. Bẹ́ẹ̀náàni fún gbogbo èdè káàkiri àgbáíyé! Gégé bí òwe tí mo pa níbẹ̀rè, èdè àyálò náà lókù nítorípé “ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n ni ò jẹ́ ká pe àgbà ní wèrè” Kíni ìtumọ̀n “SIM Card” l’édè Yorùbá? Símú Kaàdì. Ẹ tẹ̀lé mi lori Oúnjẹ Àárọ̀ Ní Ìlú Gẹ̀ẹ́sì Ọ̀rọ̀ ní sókí nípa oúnjẹ àárọ̀ tí wọ́n máa njẹ ní ìlú Gẹ̀ẹ́sì. Pàápàá jùlọ àwọn oúnjẹ tí wọ́n njẹ ní ọjọ́ ìsinmin àbámẹ́ta àti àìkú. Ìyen ni òpin ọ̀sẹ̀ tí kò l’á nsáré jẹun kí a le tètè jáde nílé lọ ibiṣẹ́ l’áàrọ̀ kùtùkùtù. Ng kò lè s’àì mẹ́nuba oúnjẹ oní kíakía tí ó wọ́pọ̀ láti jẹ lọ́jọ́ ọ̀sẹ̀. Èyí tó wọ́pọ̀ jùlọ ni kiní kan tí wọ́n fi àgbàdo àbí ọkà-bàbà ṣe tí wọ́n npè ni cornflakes. Bí wọ́n ti njẹ oúnjẹ àgbàdo yìí lèyìí. Wọ́n a dàá sí inú àwo, wọ́n a sì da wàrà tútù lée. Òmíràn nínú àwọn oújẹ àgàdo yìí ni wọ́n á ti fi ṣúgà tàbí oyin àti onírúirú nkan aládùn pa lára. Ṣùgbọ́n òmíràn a máa jẹ́ gberefu. Nígbàmíràn tí kò bá si oúnjẹ nílé, wọ́n a máa ra oúnjẹ àárọ̀ aláràjẹ lọ́nà. l’áràárọ̀ ni èrò máa ntò síwájú àwọn ilé oúnjẹ wọ́nyìí tí wọ́n sì njẹ àjẹrìn dé ibiṣẹ́. Eléyìí tí wọ́n nfarabalẹ̀ jẹ, tí wọ́n sì fẹ́ràn gidi jùlọ ni wọ́n npè ní Ọúnjẹ Àárọ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Oúnjẹ yìí lékenkà tóbẹ́ẹ̀gẹ́ ó sì jẹ́ nkan ìwúrí fún orílẹ̀èdè yìí. Orísìírísìí ẹ̀yà oúnjẹ yìí ni ó wà. Ṣùgọ́n ìyẹn di ọwọ́ ẹni tó njẹun. Èròjà tí ènìà bá fẹ́ ni ènìàn nfi síi. Bẹ́ẹ̀náàni èyí tí ènìà bá kórira, kò fa dandan. Díndín ni, bíbọ̀ ni, yíyan ni, gbogbo rẹ̀ á péjọ lórí abọ́ á máa ṣọ̀rá siìnkìn. Díẹ̀ nínú àwọn èròjà ọ̀hún rèé: Ẹyin díndín Ẹyin bíbọ̀ Ẹ̀wà inú agolo Esusun Tìmáàtì Ẹran ẹlẹ́dẹ̀ díndín Ànànmán díndín (ó dàbí dùndú) Búrẹ́dì gbẹrẹfu àbí yíyan Tíì àbí kọfí. Omi ọsàn àbí òrombó Ìrìnàjò lọ sí òkè òkúta Robin Hood Èyí ni ìrìnàjò lọ sí òkè òkúta Robin Hood. Ìlú-u Gẹ̀ ẹ́ sì ni òkúta náà wà ní ẹ̀ bá igbó nlá kan.  Ọpọ̀ lọpọ̀ abúlé àti ìgbèríko ni wọ́n yí igbó àti òkúta yìí ká. Ọ̀kan nínú àwọn abúlé náà ni Youlegrave. Tí a bá pe ìrìnàjò náà ní ìrìnkèrindò, a kò parọ́ rárá! Nítorípé láti abúlée Youlegave dé òkúta Robin Hood, bí onírìnàjò bá ṣe npọ́n òkè náà ni yó ṣe máa sọdá afárá kọjá àwọn odò kékeré.  Bí ènìà dẹ̀ ṣẹ npàdé ehoro náà ni olúwarẹ̀ á máà rí onírúirú ẹiyẹ tí wọ́n nfò káàkiri láti igi sí igi inú igbó. Bẹ́ẹ̀ náàni ènìà á tún máa láti fo àwọn odi kékèké tí àwọn onílẹ̀ kọ́ yí ilẹ̀ wọn po. Àwọn odi wọ̀ nyí jẹ́ gẹ́ gẹ́ bíi ìfàlà sílẹ̀ tí àwọn onílẹ̀ yìí fi dá ilẹ̀ tiwọn yàtọ̀ sí ti ẹlòmíràn. Youlegrave ni abúlé tí ìrìnàjò yìí ti bẹ̀rẹ̀ . Óti pé bíi ọgọ́rùún mẹ́sàán ọdún ti àwọn ènìà ti ngbé abúlé yìí. Gbogbo àwọn ilé tí wọ́n wà níbẹ̀ pátápátá ni wọ́n fi òkúta kọ́. Kò dẹ̀ sí ọ̀kan nínú àwọn ilé wọ̀nyí tí wọ́n kùn lọ́ dà rárá. Èyí mú kí gbogbo àwọn ilé yìí báramu dáadáa kí wọ́n sì gúnrégé. Àwọn ará abúlé náà sì jẹ́ onímọ̀ọ́tótó gbáà. Abúlé ọ̀ hún dára púpọ̀ , àwọn ènìà ibẹ̀ sì fanimọ́ra gidigidi. Bí wọ́n ṣe nkí aráàlú ni wọ́n nkí àjèjì. Àwọn ọ̀nà tí ó wà láàrin abúlé yìí ṣẹ tóóró-tóóró ni, wọn kò fẹ̀ rárá. Kódà ipá ni ọkọ̀ méjì ṣe ngba ẹ̀gbẹ́ arawọn kọjá. Tí ọkọ̀ méjì bá pàdé arawọn báyìí, ọ̀kan nínúu wọn gbọdọ̀ dúró sí ẹ̀gbẹ́ kan kí ó yọ̀nda ọ̀nà fún èkejì láti kọjá. Ìdí èyí ni pé ní aiyé àtijọ́ nígbàtí irú àwọn abúlé yìí fìdí múlẹ̀, ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni àwọn ṣe ọ̀nà fún. Ẹlẹ́sìn Ìgbàgbọ́ ni àwọn ará abúlé náà. Ilé ìsìn nlá kan wà láarin abúlé gangan. Ilé ìsìn náà ga sókè sooroso tóbẹ́ẹ̀gẹ́ , àwọn ará ìlú míràn lè ríi lókèrè. Ẹ̀yìn Ilé ìsìn yìí ni ọ̀nà tí ènìàá lè gbà jáde kúrò nínú abúlé, kí ó sì bẹ̀ rẹ̀ ìrìnàjòo lo sí òkè àpáta Robin Hood. Ṣùgbọ́n ènià á kọ́kọ́ pọ́n òkè kékeré kan ná. Ní orí òkè yìí ènìà á rí ibìkan tí àwọn àgbẹ̀ ilú nrọ́ imíi màlúù sí. Ó dàbí wípé ajílẹ̀ ni wọ́n nfi ìgbẹ́ẹ màlúù yìi ṣẹ nítorípé ìgbẹ́ ọ̀ hún pọ̀ púpọ̀ tí wọ́n rọ́ sí ojúkan. Òórùn rẹ̀ sì gbalẹ̀ gidi-gidi. Tí ènìà bá sì wo àyíká nṣẹ ni wọ́n fán imíi màlúù yìí káàkiri gbogbo ilẹ̀ kí koríko fi lè hù dáadáa. Oúnjẹ koríko ni ìgbẹ́ eranko jẹ́ . Tí koríko náà bá hù tán, òun náà di oúnjẹ eranko. Ó dàbí òwe Yorùbá kan “Ọwọ́ kò ní lọ sẹ́ nu kó má padà”. Tí ènìà bá rìn díẹ̀ kọjá orí òkè kékeré yìí dé ibi èbá odi tí ó yí pápá onígbẹ̀ẹ ́yìi po, ènìà ní láti fo odi ọ̀hún kọ̀ já sí òdì kejì kí ènìà tó lè tẹ̀ síwájú. Irú òkúta tí wọ́n fi kọ́ gbogbo àwọn ilé abúlé náà ni wọ́n tò lé arawọn tí odi fi ga díè tí ó jẹ́ pé àgùntàn àbí màlúù kankan ò lè fòó kọjá sí òdì kejì. Àwọn odi kọ̀ọ̀kan ní ààyè tóóró tí ènìà lè rọra rìn kọjá láì fo odi ọ̀hún, tí kò sì gba eranko kankan. Bẹ́ẹ̀náàni àwọn àgbẹ̀ míràn ṣẹ ọ̀nà tí ó gba ọkọ̀ ṣùgbọ́ n wọ́ n ṣẹ ìlèkùn-ẹranòjẹ sí ẹnu àwọn ọ̀ nà wọ̀ nyìí tí wọ́n wà ní títì ní gbogboògbà tí wọn kò sí ní lílò. Bíbẹ́ẹ̀kọ́ gbogbo àwọn eranko ìsìn wọn, ti àgùntàn ti màlúù, ò bá sálọ tán. Gbogbo ilẹ̀ẹ wọ́n ni àwọn onílẹ̀ fi odi yípo. Nítorínáà ènìà ní látimáà fo àwọn odi wọ̀nyìí kọjá nígbà kọ̀ọ̀kan. Àwọn onílẹ̀ yìí sì ti gba ènìà láàyè àti rìn lórí ilẹ̀ẹ wọn láì ṣẹ̀ṣẹ̀ tú máà tọọrọ àyè lọ́wọ́ọ wọn.  Tí ènìà bá ti fo odi mélòó kan ènìà á sọ̀ kalẹ̀ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ásì rìn kan odò kékeré. Odò yìí ni wọ́n npè ní odòo Bradford. Omi odò yìí mọ́ tóní-tóní bí enipé ó ṣeé mu ni. Inú àpáta nlá kan ni orísun odò náà wà. Àwọn ará àwọn ilú tí wọ́n wà ní ìtòsíi odò náà máa nwá si etí odò náà. Àwon àgbà a máa gba atẹ́gùn àláfíà sára. Bẹ́ẹ̀ni àwọn ọmọdé a máa ṣeré ká nígbàmíràn pẹlú ajáa wọn. Kò sí ẹja kankan nínú odò yìí rárá ṣùgbọ́n oríṣìíríṣìí ẹiyẹ ojú omi bíi pẹ́pẹ́íyẹ ni wọ́n bà sí ojú omi odò náà.  Etí odò yìí ni enìà ní láti tọ̀ títí dé inú igbó kan. Afárá kan wà ní ibi tí odò àti igbó ti pàdé. Ènìà ní láti sọdá afárá yìí kọjá sí ọ̀nà tí ó wọ inú igbó lọ. Igbó nlá ni igbó náà jẹ́ . Ṣùgbọ́n ìjọba ìpínlẹ̀ Derbyshire ti la ọ̀nà káàkiri rẹ̀ . Ìdí tí wọ́n fi la àwọn ọ̀nà wọ̀nyìí ni pé inú igbó yìí ṣẹ pàtàkì fún àwọn ará ìpínlẹ̀ òhún gẹ́ gẹ́ bíi ọ̀nà àfẹsẹ̀rìn láti ìlúdélùú. Ẹ̀yí mú ìrìnàjò nínú igbó náà rọrùn púpọ̀. Ẹ̀nìà ní láti tọ ọ̀nà tààrà tó wà létí odò títí dé òpin rẹ̀ kí ó tó tún sọdá afárá kọjá odò. Ní ibẹ̀ ni odò náà ti kọjú sí ibòmíràn. Oríṣìíríṣìí eranko ni ó wà nínú igbó náà. Ìjọba àpápọ̀ ìlúu Gẹ̀ẹ́sì ló ṣẹ ètò àti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹranko sí inú igbó nlá káàkiri ìlú. Ìdí èyí ni pé kí wọ́n wà ní òmìnira kí wọ́n sì darapọ̀ mọ́n àwọn ẹranko ìyókù nínú igbó. Ó súwọ̀n kí àwọn eranko àti ẹiyẹ wọ̀nyí máa bí síi kí wọ́n sì máa rẹ̀ síi dípò kí wọ́n wà ní àtìmọ́lé ọmọ ènìà.  Irú àwọn eranko àti ẹiyẹ tí ènìà lè rìnàkò nínú igbó náà ni ehoro, ọ̀kẹ́rẹ́, ọ̀yà, pẹ́pẹ́íyẹ, ọ̀kín, àparò, ẹiyẹlé, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ. Kò sí ẹranko búburú kankan nínú igbó ọ̀hún àyàfi àwọn kòkòrò bí agbọ́n àbí àkekèé nìkan. Oun kan ni ojú rí nínú igbó náà tí ó pani lẹ́rìín púpọ̀.  Àwọn igi kọ̀ọ̀kan wà tí àwọn ẹnìkan ya àworan sí lára. Ọ̀míràn dàbí iṣẹ́e bàsèjẹ́ àti ọmọọ̀ta. Ṣùgbọ́n ọ̀míràn dàbí iṣẹ́ ọnà gidi tí ó sì dùn-ún wò dáadáa.  Àwòrán kan wà tí ó lè ba ẹlòmíràn lẹ́ rù.  Àwòrán náà dàbíi orí abàmì ènìà kan tí ó ranjú kalẹ̀.  Ẹni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ nínú nkan báyìí lè rò pé iwin inú igi ló yọ sí òun ni!  Ṣùgbọ́n fún ẹni tí ó ní ìgboyà, àwòrẹ́rìín ni eléyìíjẹ́. Kódà ó mú ìrìnàjò inú igbó náà dùn dáadáa ni. Ní aiyé àtijọ́ ọkùnrin kan wà tí orúkọ rè njẹ́ Robin Hood. Arúfin ni ọkùnrin náà jẹ́ a sì máa jalè lọ́wọ́ àwọn olówó àti ọlọ́ á. Ṣùngbọ́n gbogbo oun tí ó njí ni ó nkó fún tálákà ati aláìní.  Nítorínáà ni gbogbo olówó ìlu bá ìjọba gbìmọ̀n pọ̀ tí wọ́n nlé ọkùnrin náà ká ṣùgbọ́n ọwọ́ ò tẹ̀ẹ́ láilái. Nítotrí ore tí ó ṣe fún aláìní gbogbo ni wọ́n ṣẹ fara mọ́ọ tí wọ́n sì tìí lẹ́hìn gbaingbain. Robin Hood jẹ́ alágbára ọkùnrin ó sì mọ ọ̀fàa ta ju enikẹ́ni lọ ní gbogbo àgbáiyé! Ọdẹ atamátàsé ni ọkùnrin ogun yìí jẹ́ ó sì tún kó àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́ timọ́ mọ́ra tí àwọn náà mọ ìjàa jà gidigidi. Inú igbó yìí jẹ́ ọ̀kan nínú ibùgbé Robin Hood àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ̀nyí.  Wọ́n sì mọ gbogbo kọ̀ọ̀rọ̀ inú igbó náà pátápátá. Èyí kún nkan tí ọwọ́ ìjọba ọ̀ fi lè kàn wọ́n rárá tí wọ́n sì fi jẹ́ àwáàrí fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ mú wọ̀n dè. Tí ènìà bá tún tẹ̀ síwájú diẹ̀ síi, á gun òkè kékeré kan á sì jáde nínú igbó náà. Jíjáde tí ènìà jáde yìí, á bọ́ sí oko nlá kan tí wọ́n fi odi òkúta yípo bíi ti àwọn oko abúlé Youlegrave tí ìrìnàjò ti bẹ̀rẹ̀. Fífò ni odi náà tí ènìà máa fi bọ́ sí inú oko nlá náà. Oko àgùntan ni oko náà nṣe.  Ótó bíi ọgọ́rùún wọ́n níbẹ̀ tí ènìà ní láti rìn kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.  Nṣe ni wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́ tí wọ́n njẹ koríko lọ.  Lẹ́ẹ̀kọ̀kan wọ́n á gbójú sókè wòyàn ṣùgbọ́n tí ènìà kò bá ti dẹ́rù bà wọ́n, wọ́n á padà sí koríko jíjẹ. Ẹranko oníwà pẹ̀lẹ́ gbáà ni àgùntàn nṣe. Ìṣesíi wọ́n múni rántí ọ̀rọ̀ kan nínú Bíbélì tó wípé “Ẹ̀mi ni olùṣọ́ àgùntàn rẹ, ìwọ kì yíò ṣe aláìní”.  Òkondoro ọ̀rọ̀ gidi ni eléyìí jẹ́ tí ènìà bá ṣe àgbéyẹ̀wò ìgbésí aiyé àwọn àgùntàn wọ̀nyìí! Nkan tí ó jẹ́ ìyàlẹ́ nu ní pé gbogbo oko tí ènìà nkọjá ni kò ní pàdé àgbẹ̀ àbí onílẹ̀ kakan rárá.  Àfi àwọn ẹranko nìkan.  Nṣe ni wọ́n fi àwọn ẹranko wọ̀nyí sílẹ̀ kí wọ́n máa báíyé wọn lọ. Gbogbo ìrìn tí ènìà ti rìn nígbà tí ó bá kọjá oko àgùntà yìí tán á ti máa fẹ́ tó bíi wájàtí mẹ́ta sí mẹ́ta-àbọ̀.  Ebi á sì ti bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí ní pá ènìà tí kò bá gbé oúnjẹ dání.  Òngbẹ á sì ti máa gbẹ ènìà pẹ̀ lú.  Ó dàbí pé àwọn oní òwò oúnjẹ agbègbè yìí ti ṣe ìwádìí ibi ti ebi àbí òngbẹ á ti bẹ̀ ẹ̀ rẹ̀ sí ní máa dàmú àwọn onírìnàjò.  Nítorípé bí ènìà bá ṣe jáde kúrò nínú oko àgùntàn ni á ṣe kòóngẹ́e atọ́ka tí wọ́n ṣe síbẹ̀.  Atọ́ka yìí júwèé ilé kan lókèrè tí ìtura oúnjẹ àti nkan mímu onírúirú wà fún àràjẹ.  Ìyá arúgbó kan ni ó ntọ́jú ilé ìtura yìí. Òun náà sì ni ó nta oúnjẹ àti nkan mímu níbẹ̀.  Arúgbó náà fẹ́ràn láti máà bá àwọn onírìnàjò rojọ́ púpọ̀ nítorípé òun nìkan ni ó wà ni ilé yìí tí ó dádúró tí ó sì jìnà sí abúlé adúgbò ibẹ̀. Àgbàlagbà obìrin yìí kìí rí ẹlòmíràn bá sọ̀rọ̀ nítorípé ọkọ rẹ̀ ti ṣaláìsí. Arúgbó náà jẹ́ ènìà rere, àánú rẹ̀ a sì máa ṣe gbogbo onírìnàjò. Wọ́n a sì máà yọ̀ mọ́ ọ tí wọ́n á máa báa rojọ́ dáadáa. Ìyá yìí mọ ọ̀nà tí ènìà lè gbà dé ibi àpáta Robin Hood ní kíákíá, ó sì júwèé rẹ̀ fúni tí ènìà bá wí fún-un pé ibẹ̀ ni òun nlọ. Ọ̀nà tí arúgbó náà júwèé tọ orí òkè kékeré kan lọ. Koríko hù sí orí òkè náà ṣùngbọ́n ó dàbí ẹnipé ẹnìkan nṣe ìtọ́ jú rẹ̀ nítorípé koríko ọ̀hún kò hù kọjá ààlà.  Ní ìgbà òtútù nìkan ni yìnyín máa nṣábàá rọ̀ . Ṣùgbọ́n lórí òkè àbí àpáta tí ó bá ga sókè tó, yìnyín a máa rọ̀ nígbàkígbà tí ó bá tutù tó nítorípé òtútù mú lókè àpáta ju pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ. Nítorínáà ènìà máa nṣábàá bá yìnyín tí ó rọ̀ sóríi koríko orí òkè wọ̀nyìi. Nígbàmíràn àwọn ọmọdé á máa ṣeré lóríi yìnyín náà.  Ènìà tún lè rí àwọn ère tí wọ́n fi yìnyín yìí gbẹ́ síbẹ̀.  Tọmọdé tàgbà ni wọ́n fẹ́ràn láti máa fi yìnyín gbẹ́ ère.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ère ọ̀hún ni wọ́n ti máa bẹ̀rẹ̀ sí yòòrò nígbàtí ènìà bá rí wọn nítorípé yìnyín ò kí npẹ́ yòòrò tí òtútù bá káwọ́ nlẹ̀ díẹ̀ àbí tí òrùn bá ràn síi.  Tí ènìà bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, á bọ́ sí ojú ọ̀nà tí àwọn àgbẹ̀ nlò fi kó ẹrù àti irinṣẹ́ wọn pẹ̀lú ọkọ̀ akẹ́rù.  Tí yìnyín bá rọ̀ sí ojú ọ̀nà yìí wọ́n á fi ọkọ̀ tí wọ́n fi nkó ilẹ̀dú kó yìnyín ojú ọ̀nà sí ẹ̀gbẹ́ kan, kí ó má fi dí ọkọ̀ wọn lọ́ nà. Ọ̀nà yìí já sí ọ̀nà míràn tí ènìà bá tọ̀ọ́ já tán. Ọ̀nà nlá yìí ni àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti ọkọ̀ akérò ngbà láti ìlú dé ìlú. Ní àbáwọ ọ̀nà yìí atọ́ka míràn wà tí ó tún júwèé ilé oúnjẹ arúgbo ẹ̀ẹ̀kan.  Abájọ tí ìyà arúgbó náà ṣe mọ ọ̀nà yìí dáadáa.  Ènìà láti rìn lórí ọ̀nà nlá yìí nítorípé kò s�� ọ̀nà àfẹsẹ̀rìn kankan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà nlá yìí bí a ṣe lè ríi lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀nà nlánlá míran.  Nítorí èyí, ènìà ní láti fetí sílẹ̀ gidigidi kí ó máa fura bí ó ṣe nrìn lọ kí ó lè yàgò lọ́nà tí ọkọ̀ bá nbọ̀.  Ewu nbẹ fún onírìnsè lójú ọ̀nà yìí nítorípé àwọn awakọ̀ míràn a máa wa àwàsaré.  Ènìà ní láti ṣọ́ra kí ọkọ̀ má lọ gbá olúwarẹ̀ . Ọkọ̀ tí ó nbọ̀ láti iwájú ṣeérí láti òkèrè nítorípé ọ̀nà tààrà ni ọ̀nà nlá yìí nṣe. Ní apá ọ̀tún ọ̀nà nlá yìí ni ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ti nfọ́ òkúta nlánlá lára apáta. Òkúta yìí ni wọ́n fi nkọ́lé, tí wọ́n sì fi nkọ́ gbogbo àwọn odi tí wọ́n fi nyí ilèe wọ́n po.  Kódà ibẹ̀ ni wọ́n ti nfọ́ gbogbo òkúta ti wọ́n nlò ní ìpínlẹ̀ Derbyshire káàkiri.  Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti nfọ́ òkúta níbẹ̀.  Gbogbo ibẹ̀ sì ti di kòtò nlá gidi gaan ni.  Kòtò ọ̀hún tóbi tó bíi abúle kan sí méjì! Kìí ṣe kòtò kékéré rárá.  Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba nìkan ní wọ́n ní àṣẹ láti wọ ibẹ̀ . Kò sáàyè fún ẹnikẹ́ni míràn. Ti ènìà bá rin ọ̀nà yìí díẹ̀ , yó máa wo òkúta nlá kan lókèrè.  Nígbànáà ni ènìà yó rí ọ̀nà kékeré tó lọ́ tààrà sí ẹsẹ̀ òkúta nlá yìí.  Bí ènìà bá ṣe nsúnmọ́n-ọn lọ ni yó máa pàdé àwọn ènìà míràn tí wọ́n gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ dé ibi ọ̀kúta yìí.  Bẹ́ẹ̀náàni òkúta ọ̀hún á máa ṣe bí ẹ̀nipé ó nparadà.  Á kọ́kọ́ jọ ilé nlá kan. Á tún paradà á dàbíi ère kìnìún nlá.  Ó dìgbà tí ènìà bá súnmọ́n-ọn tán kí ó tó ríi pẹ́ àwọn òkúta jànkànjànkàn tí wọ́n tò lé arawọn ni. Òkúta nlá yìí ní ibi méjì tí ó ga sókè jù ní igun méjéèjì.  Alákùrin àtijọ́ Robin Hood ni ìtàn kán sọ fúnwa pé ó fò láti igun sosoro ìkíní sí ìkejì ní ìgbésẹ̀ ẹyọọ̀kan soso! Ìdí lèyí tí wọ́n fi npe òkúta yìí ní Ìgbésẹ̀ Robin Hood. Ọ̀pọ̀ lọpọ̀ ènìà ni wọ́n máa nwá sí ibi òkúta yìí láti ìtòsí àbí ọ̀nà-jíjìn. Àwọn míràn máa nwá pọ́n òkúta yìí ni, nítorí ó dùn-ún pọ́n gidigidi fún wọ́n.  Ó di dandan kí olúwarẹ̀ náà gbìyànjú àti pọ́n-ọn dókè. Ibi a wí ni a dé yìí o! Gbogbo ìrìnàjò náà gba bíi wákàtí márùún. Tí ènìà bá ṣeré díè tí ó pọ́n òkè tí ó ya àwòrán tán, ó di ilé! Oúnjẹ wo ni àwọn ènìyàn mo ìlú tie mó? Àsìkò ìdá ara wa l'ẹ̀kọ́ Ẹ parí òwe yìí A kú ọjọ́ mẹ́ta oooo. Se àlàáfíà ni gbogbo wa wà Ẹ kú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ooo Ọ̀jọ̀gbón Akinwándé Oluwo̩lé Babátúndé S̩óyinká Èmi náà fẹ́ràn orin yìí púpọ̀ láti ọwọ́ olóògbé Sikiru Àyìndé Barrister. Ẹ̀yin ńkọ́? Kíni orúkọ Bàbá yìí? Ipa wo ni wón máa ń kó jù nínú eré tí wọ́n máa ń ṣe? IṢẸ́ ẸNI Iṣẹ́ ẹni ni iṣẹ́ ẹni Má tijú iṣẹ́ rẹ Ikán kì í tijú à ń mọlé Èèrà kì í tijú à ń lànà Alápàáǹdẹ̀dẹ̀ kì í tijú à ń fò kiri ní gbangba Iṣẹ́ ẹni niṣẹ́ ẹni Má tijú iṣẹ́ rẹ Bígi lo bá ń gé ṣowó Bí wọ́n sì gbà ọ́ pé kí o gbálẹ̀ ọjà Bíràn-ánṣẹ́ lo sì jẹ́ lábẹ́ ìjọba Iṣẹ́ ẹni ni iṣẹ́ ẹni Má tijú iṣẹ́ rẹ Ò bá à ṣàgbẹ̀ Ò bá à ṣakọ̀wé Bó o jẹ́ ìnájà Bó o jóníwóróbo Iṣẹ́ ẹni niṣẹ́ ẹni Ṣiṣẹ́, iṣẹ́ kì í pani Àìṣe rẹ̀ gan-an làbùkù..! Bí ẹ bá rántí rẹ,̀ ẹ kọ "Bẹ́ẹ̀ni", bí ẹ ò bá rántí rẹ̀, ẹ kọ "bẹ́ẹ̀kọ́", bí ẹ ò bá gbọ́ ọ rí, ẹ kọ "Mi ò mọ̀ ọ́n o Kíni ẹ̀yin náà rí sí ọ̀rọ̀ yìí. Ǹjẹ́ o tọ̀nà kí ọkùnrin máa náà obìnrin. Ọkùnrin èyí kìí se ọkùnrin lásán óò aṣojú ni ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà Oṣù Agẹmọ Ẹ dárúkọ àwọn tí ó wà nínú àwòrán yìí Èwo nínú àwọn àgbàdo yìí ni ẹ fẹ́ràn ju. Ní tèmi àgbàdo sísun ni Ikú tún ti wọ agboolé òṣèré Yorùbá. Àgbà òṣèré Fasasi Olabankẹwin tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Dagunro ti dágbérejẹ fàyè ni Òwúrọ̀ yìí. Ikú ikú ikú Kílódé? Ẹ sọ ǹkan ẸYỌ KAN tí ẹ mọ̀ NÍPA Olóògbé Ǹjẹ́ ẹ rántí orin yìí? Kí le ri si àwòrán yìí Ankara lórí gini Oriki Ibeji: Wíníwíní lójú orogún Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀, Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún, Ẹdúnjobí, ọmọ a gbórí igi rétẹréte, Ọkàn ń bá bí méjì ló wọlé tọ míwá, Ọ́bẹ́kíṣì bẹ́kéṣé, Ó bé sílé alákìísa, Ó salákìísà donígba aṣọ. Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá, Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọmọ. Bi Táyélolú ti nló ni iwájú, Bééni, Kehinde ń tó lẹ́yìn, Táyélolú ni àbúrò, Kehinde ni ẹ̀gbọ́n, Táyélolú ni a rán pé kí o ló tó ayé wò, B'ayé dára , bi ko dára O tọ́ ayé wò, Ayé dun bi oyin Táyélolú, Kehinde, ni mo ki Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀ O dé ilé ọba tẹ̀rín-tẹ̀rín, Jẹ́ kí nrí jẹ, kí n rí mú. Orí yéye ní'mògún Kìí ṣe gbogbo ẹni tọ́' lọ́pàá mú ni ọ̀daràn, Kìí ṣe gbogbo ẹni tọ́ wà ní àhámọ́ ni ó dáràn ìjọba, Àìmọye, àìmọwọ́, mẹsẹ̀ tó ti dèrò ọ̀run, Nínú àsìmú tàbí àrìnfẹsẹ̀sí, Ẹlòmíràn lè sọ̀rọ̀ lásán kí ó ti bè dèrò ẹ̀wọ̀n, Tàbí kó yọ sálákeji, Ikú àìmọ̀dí kò gbé yín, Àbí kí ni ka tí pe o, bàbá tó fọmọ fọ́kọ tí ìyàwó ń bá ọkọ dọ́wẹ̀kẹ́ẹ̀ nílé ìwẹ̀, nígbà tó ń kín lẹ́yìn "baálé mi, bí ẹ ti jánjá nìyí tí gbogbo ayé ń bẹ̀rù yín", Èyí bọ̀ sí àpò ìbínú ọkọ, Kí ìyàwó lè mọ bí agbára òun ṣe tó, Oni kí wọn ó lọ gbori bàbá ìyàwó wá, Bàbá kú ikú àìmọ̀dí, Láìmọ̀ ibi tí ìdààmú òun ti wá, Orí yéye ní'mògún Tàìsẹ̀ ló pọ̀. Èdùmàrè má jẹ́ kí gbogbo wa jìyà àìmọ̀dí. Àmín Àṣẹ Èdùmàrè Ó pé Ogún ọdún lónìí tí àwọn ológun gbé ìjọba fún alágbádá ní Orílè-èdè Nàìjíríà. Ǹjẹ́ Itesiwaju tí dé bá wa ní orílè èdè Nàìjíríà? "Ibo là ń lọ ní orílè èdè Nàìjíríà, Ibo là ń lọ náà, Mo nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀ èdè mi ti ṣe Nàìjíríà, Mo fé mọ ibi tí a ń lọ ní orílè èdè Nàìjíríà. " A kú ayẹyẹ gbogbo ọmọ orílè èdè Nàìjíríà. Kíni àkọlé eré yìí Òwe Yorùbá Orúkọ wo ni ẹ̀yin mo ǹkan ìṣeré yìí sí. Àwọn ọmọ ajebota ò lé mo ooo Ǹjẹ́ ẹ lè dárúkọ àwọn mẹ́rẹ̀rin tí ó wà nínú àwòrán yìí. Ẹsẹ́ adúpẹ́ adúpẹ̀pẹ́ òkun. Èdè Yorùbá ò ní parun A Kú Àmójúbà Oṣù Ramadana O! Mo kí gbogbo Mùsùlùmí lọkunrin àti lobinrin, ní orílè èdè Nàìjíríà àti ní gbogbo àgbáyé pé, a kú ìdásẹ̀ wọ oṣù alápoǹlé nii tí ṣe oṣù Ramadana, oṣù yọ́ ẹ̀sẹ̀ yọ́ ẹ̀sẹ̀, ẹ̀mí gbogbo wa tí a bẹ̀rẹ̀ rè ni yíò gbájá nínú ìlera tó péye àti àlàáfíà. Ọdún ayọ̀ laa ṣe láṣẹ Èdùmàrè Ẹni tí ó ń ṣiṣẹ́ déédé, ó yẹ kí ó lásìkò ìgbádùn nítorí isẹ́ lógún ìṣẹ́. Ẹ kú ìsinmi ọjọ́ òṣìṣẹ́! Ìyàwó Gbenga Adeboye àti àwọn ọmọ wọn David àti Elijah. Ọlọ́run a wà pẹ̀lú yín. Ó pé ọdún mẹ́rìndínlógún tí tí fi wá sílè. Èdùmàrè jọ̀wọ́ báwa dẹlẹ̀ fún Èlíjà Ẹ wá je àgbàdo Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ ìtàn bii, tani àwọn tí ó wà nínú àwòrán yìí Ǹjẹ́ ẹ̀yin rántí orúkọ ti a n pe kòkòrò yìí àti ǹkan tí àwọn ọ̀dọ́mọdé'bìnrin máa fi ń ṣe. Ajepákó nì kan ló lè mon. Ǹjẹ́ ẹ mọ àwọn olórí Nàìjíríà dada Ìbéèrè ńlá Àyẹ̀wò ojú. Ẹ ko nọ́mbà tí ẹ rí Ọ̀RỌ̀ ìṣítí Ọmọdé yìí máa ń tẹ́lẹ̀ àwọn òbí rẹ̀ lọ sí oko. Bàbá ọmọdé yìí ní bàntẹ́ kan, bàntẹ́ jẹ́ aṣọ kékeré tí àwọn àgbàlagbà máa ń wọ̀ sí abẹ́ aṣọ. A lè fi bàntẹ́ wé pátá àwọ̀tẹ́lẹ̀ òde òní. Gbogbo ìgbà ni ọmọdé yìí máa ń tọju ìbàntẹ́ bàbá rẹ̀ nípa fífọ̀ àti kíká wá sí ilé. Ní ọjọ́ kan, ọmọdé yìí gbàgbé bàntẹ́ sí oko, ó dé ilé tán kí ó tó rántí pé òun kò mú bàntẹ́ wá sí ilé, ṣùgbọ́n kìn ni ó bá pàdé lóko? Bí ọmọdé yìí ṣe ní kí òun náwo mú bàntẹ́ ni ó gbọ́ tí bàntẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí kọrin báyìí pé: Bàntẹ́ Ọmọ gbàgbé mi sóko Ègbè Bàntẹ́ Bàntẹ́ Ó tún padà wá múni Ègbè Bàntẹ́ Bàntẹ́ Ó di gbì okú lọ Ègbè Bàntẹ́ Bàntẹ́ Ó di gbì ikú dé Ègbè Bàntẹ́. Bí bàntẹ́ tí dáké orin, ni ọmọdé yìí fò sánlẹ̀ ó sì kú. Nígbà tí àwọn òbí ọmọ yìí retí rè tí wọn kò ríi ni àwọn náà bá gbéra ó di oko. Nígbà tí wọ́n dé oko, wọ́n rí òkú ọmọ wọn nílè àti bàntẹ́ tí ọmọ padà wá mú lóko. Bí àwọn òbí ọmọ yìí ti gbée nílè tí wọ́n sì tún nawọ́ láti mú bàntẹ́, ìyàlẹ́nu ni ó jé fún wọn pé orin ni bàntẹ́ fi dá wọn lóhùn bíi ti àkókò. Bí bàntẹ́ tí parí orin rè ni àwọn òbí ọmọdé yìí náà fò sánlẹ̀ tí wọ́n kú. Lẹ́hìn èyí ni àwọn aládùúgbò náà wá sí oko ṣùgbọ́n bákan náà ni. Ìròyìn wá kàn dé ọ̀dọ̀ ọba ìlú. Ọba pàṣẹ pé kí ọ̀sanyìn ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́wàá ó lọ mú bàntẹ́. Ọ̀sanyìn ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́wàá náà lọ ṣùgbọ́n òun náà kú sí oko. Gbogbo àwọn ọ̀sanyìn ọba náà ni wọ́n lọ tí àwọn náà sì kú sí oko. Nígbà tí ó pẹ́,ọ̀sanyìn ẹlẹ́sẹ̀ kan yọjú síta, ó sọ pé òun yóò mú bàntẹ́ wá sí ilé. Gbogbo ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣe yẹ̀yẹ́ pé ohun tí ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́wàá kò rí mú wálé ni ẹlẹ́sẹ̀ kan fẹ́ dánwò. Wọ́n tún sọ pé "ibi tí èfúùfù ti ń gbé kẹ̀tẹ̀pẹ̀ Ogi tí èlùbọ́ ni òun yóò ṣe ọmọ ìta". Ọba sọ fún àwọn ènìyàn kí wọ́n fi Ọ̀sanyìn ẹlẹ́sẹ̀ kan sílè kí ó gbìyànjú kí ó pa itú ọwọ́ rẹ. Ọ̀sanyìn ẹlẹ́sẹ̀ kan lọ sí oko, ó pa itú ọwọ́ rè ó sì mú bàntẹ́ wá sí ilé. Ìtàn yìí kó wa wípé kò yẹ kí á máa f'ojú tẹ́ńbẹ́lú ẹnikẹ́ni nítorí ẹ̀dá kò láròpin.. Mo lérò wípé ẹ gbádùn Àlọ́ yìí. Ẹsẹ́ púpọ̀. Ó yá ẹ pa òwe kan tí Ọ̀RỌ̀ jẹ jáde nínú è. Fún àpẹẹrẹ "Ààbọ̀ Ọ̀RỌ̀ l'àá sọ fún ọmọlúwàbí, tí ó bá dé inú rẹ̀ á di odindi." Sẹ́ láyà lètò, ètò ni sẹ́ láyà Mò ń ṣe àárò ìwé yìí gidigidi ní óò. Ọ̀kan nínú àwọn gbólóhùn tí mo fẹ́ràn láti ma kà nínú ìwé Alawiye rẹ. Èwo ni ẹ̀yin fẹ́ràn? Lẹ́yìn tí ilé alájà mẹ́ta dà wó ní ìlú Èkó l'Ọjọru níbi tí Ogún èèyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn, atún gbó wípé ilé alájà mẹ́ta mìíràn tí wọ́n ń kọ lọ́wọ́ tún ti wó ní ìlú Ìbàdàn. Èdùmàrè fún gbogbo àwọn tó fi ara pa ni ìwòsàn to péye Èdùmàrè má jẹ́ kí á sí nílé lọ́jọ́ tebi ń Àṣà ilà Kíkọ ní Ilè Yorùbá Bí a bá wo ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá ní Orílè-èdè Nàìjíríà, á ri wípé oríṣiríṣi ilà lọ máa ń wà lójú àwọn ènìyàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni kò sì mọ ìdí rè tí a fi máa ń ko ilà. Kí wá ni ìdí rè tí a fi ń ko ilà? Ìdí rè tí a fi ń ko ilà pín sí ọ̀nà méjì. Nígbà àtijó, ogun àti ọ̀tẹ̀ pò ní orílè èdè Nàìjíríà. Ní àkókò yìí ni ọmọ ń sọnù lairo tẹ́lẹ̀. Àwọn alágbára ńkọ́ àwọn ọmọ ẹnití kò ní agbára bí ti wọn tà. Bí wón ti ń kó ọmọ, bẹẹni wón ńkọ́ aya. Bẹẹni ọ̀pọ̀ géndé (youth) ń sọnù, tí à nfi wón ṣe àwárí. Bí a ti ń kọ wón là ń tawon lé'rú fún àwọn orílẹ̀ èdè míràn. Bí àwọn tí a tà lé'rú wọ̀nyí, yálà láti ìdílé kan náà tàbí ìlú kan náà bá pàdé, nwon kò ní mọ ara wọn rárá. Ṣùgbọ́n àwọn àgbàlagbà ronú pé ó ye kí kíni kan bí àmì wà, èyí tí wọn yóò fi máa mọ ara wọn. Tí won ò sì lè sọ léṣèkannaa ìlú tí ènìyàn kan ti wá ní kété tí a bá rí. Ọgbọ́n ìlà kíkọ yìí kì í ṣe ti gbogbo orílè èdè yìí ni láti ìbẹ̀rẹ̀ bikose ohun tí àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè yí jogún láti Iwọ̀ Oòrùn níbi tí àṣà náà tí kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Àlàyé kejì fún ilà kíkọ ni pé bóyá àwọn ènìyàn Iwọ̀ Oòrùn níbi tí àṣà yí ti bẹ̀rẹ̀ rò pé yóò bùkún ẹwà ara wọn nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Bí a bá wojú ẹlòmíràn nínú àwọn Ọkùnrin tàbí àwọn obìnrin tí ó kó ilà, a ó ri pé ilà náà dára púpọ̀ lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn. Dájúdájú, àṣà láti bù sí ẹwà ara ni irú àwọn bẹ́ẹ̀ ka ilà kíkọ sí. Bí a bá wo fínnífínní, a ó ri pé ilà yí yàtọ̀ sí ara wọn láti agbègbè sí agbègbè tàbí ìlú sí ìlú níbomíràn . Àwọn Ọ̀yọ́ ní kọ oríṣiríṣi Àbàjà, Pẹ́lẹ́ àti Túré. Wọn tún ń kọ Àbàjà mẹ́ta-mẹ́ta , tàbí Gọ̀mbó, Kẹ́kẹ́ àti Gọ̀mbó papò. Àwọn Èkìtì á bù mẹ́ta-mẹ́ta tí ó gbọọrọ, tàbí ẹyọ kan ṣoṣo tí ó gbọọrọ, tàbí mẹ́ta ọ̀rọ́ lórí mẹ́ta ìbú tí ó gbọọrọ. Àwọn Ẹ̀gbá ni nkọ mẹ́ta-mẹ́ta tí kò gùn tí kò sì gbọọrọ. Àwọn Ìjẹ̀bú a máa kọ mẹ́ta-mẹ́ta tàbí mẹta lókè, mẹ́ta ní ìsàlè rè. Àwọn Òwu náà ń bu Àbàjà, wón sì ń bu Kẹ́kẹ́ pẹ̀lú. Púpọ̀ nínú àwọn Ifẹ̀ kìí kọlà, ṣùgbọ́n àwọn míràn nkọ mẹ́ta-mẹ́ta nígbà míràn. Àwọn Ìjẹ̀sà ńkọ mẹ́fà. Òndó ńkọ mẹ́ta-mẹ́ta. Àwọn Iyagba ńkọ mẹ́ta-mẹ́ta tí ó fẹẹ papọ̀ l’eba ẹnu wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé la ti pa asa yìí rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé wà tí kò fẹ́ fi àṣà yìí sílè rárá. Àpẹẹrẹ àwọn ilà tí a ń kọ rèé Ìròyìn ń jẹ́ ká mọ̀ wípé Ọ̀gbẹ́ni Olatoye Temitope Sugar kú láti ibo tí wọ́n yìn mọ Ó yá ẹ pa òwe kan tí ó ní OMI jẹ jáde nínú è. Fún àpẹẹrẹ "OMI tí èyàn máa mu, kò ní ṣàn kọjá rẹ̀." Sẹ́ láyà lètò, ètò ni sẹ́ láyà. Ìdí nìyí tí Àwọn Yorùbá fi ma ń sọ pé "Ẹ̀kìrì bíkan pàdímó Ǹjẹ́ ẹ rántí ìtàn yìí nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé tí a kà ni ọdún díè sẹ́yìn. Sẹ́ ẹ̀yin ka ìwé náà. Fún gbogbo àwọn ÌYÁ káàkiri àgbáyé. Ẹsẹ́ púpọ̀ fún isẹ takuntakun yín lórí wa. Ǹjẹ́ ẹ rántí ìtàn yìí nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé tí a kà ni ọdún díè sẹ́yìn. Sẹ́ ẹ̀yin ka ìwé náà. Ṣé ẹ mọ àdúgbò ìlú yín dada Òní ọjọ́ Kàrún oṣù Ẹrẹ́nà ni Oluségun Àrèmú Ọbásanjọ́ pé ọdún méjìlèlọgọ́rìn lókè erùpẹ̀. Ẹ jẹ́ ká kí bàbá kú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí èmi yín a gùn. Ǹjẹ́ ẹ rántí eré yìí? 1) Dárúkọ Òṣèrè ọmọ kékeré? 2) Dárúkọ àkọlé eré yìí? O yá ẹ pa òwe kan tí “ỌMỌ ” jẹ́ jáde nínú rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ; “Bá mi na ỌMỌ mi, kò dẹ́nú ọlọ́mo.” Sẹ́ láyà lètò, ètò ni sẹ́ láyà. Ìtàn tí ó rọ̀ mọ́ ìbéèrè yìí "Ẹja Ni Àbí Akán" Akàn àti Ẹja jẹ́ pàtàki nínú àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yeyemoja Olókun. Ní ọjọ́ kan ni Yeyemoja pe ọmọ rẹ̀ Ẹja (fish) pé kí ó lo bá òhun sin gbèsè. Nígbà tí Ẹja dé ọ̀dọ̀ onígbèsè, ni ó bá barajé, Ó ṣòrọ̀ àbùkù òhun ẹ̀tẹ́ sí onígbèsè. Ìwà ìbàjé yìí, mú kí inú bí onígbèsè, ó pinu pé òhun kò ní gbèsè kan san. Ẹja Korí sílé, kò rí gbèsè náà gbà, ó relé pẹ̀lú ọ̀fọ̀; Ọjọ́ kejì ọjà. Yeyemoja bá tún ké sí Alákàn pé kí ó bá òhun lọ sin gbèsè. Nígbàtí Alákàn dé ọ́dọ̀ onígbèsè , tí ìrèlè ìwà pẹ̀lú ìtẹríba tí a mọ sí Ìwà ọmọlúwàbí ni Alákàn fi jísé fún onígbèsè. Yorùbá bò wọn ní; Ọ̀rọ̀ tútù ní ń mú obì jáde lápò, Ọ̀rọ̀ burúkú idà ni ń yọ. Báyìí ni onígbèsè bá wọlé, ó sì san gbèsè fún Alákàn , ní Alákàn bá kóredélé. Onígbèsè bá gbéra ó di ilé Yeyemoja Olókun Seniade, Nígbàtí ó dé ọ̀dẹ̀dẹ̀ Yeyemoja, ó wípé, nígbàkúgbà tí ó bá fẹ́ rán oníṣé sí òhun kò dákun má ṣe rán Ọmọ rẹ̀ Ẹja sí òhun mó, Wípé ọmọ rẹ̀ Alákàn ni òhun fẹ́. È yìí ló mú àwọn àgbà Yorùbá wípé; "Àṣẹyẹ̀ ni ti Alákàn àmúbó ni ti ọmọ Ẹja" Ìdí nìyí tí àwọn Yorùbá ṣe máa ń ṣe àsamọ̀ pé; Ẹja N ' B'Ákàn Òní ni àyájọ́ ọjọ́ Èdè abínibí ni gbogbo àgbáyé, ẹ dákún ẹ jẹ́ kí á gbìyànjú láti sọ Èdè Yorùbá sì ara wa lónìí àti lọ́jọ́ gbogbo, láti fi ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ yìí nítorí pé Èdè Yorùbá Rewà púpọ̀. Èdùmàrè báwa fún Babasuwe ní àlàáfíà tó péye ẹ pa òwe kan tí “ÌFẸ́” jẹ́ jáde nínú rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ; “Yàrá kékeré gba ogún ọ̀rẹ́, tí ÌFẸ́ bá wà láàárín wọn.” Sẹ́ láyà lètò, ètò ni sẹ́ láyà. Àgbàrà òjò ò lòun kò ní iléé wo, sùgbọ́n onílé ni kòní gba fún un” Sẹ́ láyà lètò, ètò ni sẹ́ láyà Ógbenután Gàárì ló le ṣé. Ǹ jẹ́ a tún lè rí àwọn ìwé yìí ra Tí ẹ bá mọ ìbásepọ̀ tí ó wà láàrin àwòrán yìí ẹ sọ fún wa. Seere Ẹ̀rẹ̀lẹ́ Ẹrẹ́nà Igbe Ẹ̀bìbí Okúdù Agemọ Ògún Ọ̀wéwè Ọ̀wàrà Béelú Ọ̀pẹ. Àwọn Onka oṣù kọ̀ọ̀kan nìyí ni èdè Yorùbá wá. Ẹjẹ́ kí á kọ́ àwọn ọmọ wa ní ìgbélárugẹ Ásà, Èdè àti Ìṣe ilẹ̀ Yorùbá Àṣà ilà kíkọ Eégún Aláré Ǹjẹ́ àwọn lọ́balọ́ba nípa tí wọ́n ń kọ nínú òṣèlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà? Ǹjẹ́ ipa wọn mú ìlọsíwájú wá fún ìran Yorùbá? Ẹjẹ́ ká gbé ìbéèrè méjì yìí A kú ewu ọdún tuntun, ọdún ayọ̀,ìdùnnú, oríre ni yíò je fún gbogbo wa láṣẹ èdùmàrè... Ẹsẹ́ púpọ̀ fún àti leyin yín pẹ̀lú ÈDÈ YORÙBÁ REWÀ láti ọdún tí a ti bẹ̀rẹ̀, ọdún 2019 a tún fún yàtò. ètò láti sílè fún ọdún 2019 láti jé kí èdè, àṣà àti ìṣe wá Ẹ kú dédé àsìkò yìí gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí, Èyí ni láti kéde wípé láti ọlá lọ a ó bẹ̀rẹ̀ si ká ìwé Ègún Aláré tí A fi àsìkò yìí kí gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí kú ọdún Ẹsẹ́ púpọ̀ fún ìfẹ́ àti iranlowo yín fún ìtèsíwájú èdè,àṣà àti ìṣe Yorùbá. Fún gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí. Òkèlè wo ló dára jù láti fi jẹ ọbẹ̀ yìí ÌWÀ Ẹ̀̀DÁ Ẹ̀̀dá nimí, mo sì ń fi ìgbà gbogbo dárà. Mo gbágbè adẹ́dà, mo sì ń dá wu ìwà tèmi. Èmi kò mọ̀ pe olùbéèrè á bimí, b��́ẹ̀ sì ni adẹ́dà á şe ìbéèrè pẹ̀lú. Mo wu ìwà títí: mo wu ìwà tí kò gbeni; ìwà tó mú ni şìnà, mo rin ọ̀nà tí kò pé; ọ̀nà tó mú ni jẹ̀bi. Mo kọ ọ̀rọ̀ àgbà, mo fi etí pa ìşítí àgbà, mo wu ìwà tó tọ́ ní ojú mi, bẹ́ẹ̀ ni mo şe fi etí gún lágídi ọ̀rọ̀ ẹbí pàápàá. Mo kó ọ̀rọ̀ ọba ìlú pàápàá jùnù, tèmi ló tọ́, èyí tó wùnmí ni mo şe. Mo wu ìwá burúkú tẹ́rùn. Mo şe ìşe tani á múmi, mo sì şe é ní àşekún. À şé ohun tí a bini á kúkú bini. Mo şe ìwà burúkú, ó kún gédégbé, ẹ̀yìn lẹ́yìn ni mo wá tẹ. Mo tẹ́ kọjá sísọ! Kí lẹ rò pé ó şẹlẹ̀ gan? Ìtàn 'Ìwà ẹ̀dá' tẹ̀síwájú lọ́la. Ẹ şeun! Láti ọwọ́ Àdìgún ÌKÍNI NÍ ÈDÈ YORÙBÁ. APÁ KÌÍNÍ Yorùbá ni kíkí fún gbogbo àsìkò ọjọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ àti èto.̀ Fún àpẹrẹ: a lérò wípé àwọn ti a kọ si ojú ìwé yi, àti bi a ti le pe ìkíni kankan a wúlò fún yin. Ẹ kú ìtàdí. Ẹ kú ìrejú. Ẹ kú àlejò Ẹ kú ìjókòó o E kú ọjọ́ mẹ́ta Ẹ kú àmójúbà Ẹ kú iso Ǹjẹ́ ọmọ obìnrin rẹ le múra báyìí Ojúlarí Ọ̀rẹ́ ò dénú IȘẸ́ OLÙKỌ́ Ẹ bá mi kírà, Fún gbogbo olùkọ́ ayé pátá. Ișẹ́ ńlá tó yakin ni wọ́n ń ṣe. Àwọn lÒdùdù tí í du orí ìlemèrè. Tí kì í jẹ́ kórí ìlemèrè ó bàjẹ́. Tọ̀sán tààjìn, Ni wọ́n fi ń tú ayé ọmọ ọlọ́mọ ṣe. Ẹ̀yin lẹ kọ́ Ọba lẹ kọ́ ìjòyè ìlú. Ẹ̀yin lẹ kọ́ Sínétọ̀ kọ́ Olórí-oko. Lẹ́yìn Adániwáyé, Àlá ọmọ ẹ̀dá kan ò le ṣe, Bí ò sí ti tíșà lókè èèpẹ̀. Onínúure bíi tíșà ò sí láyé. Olùkọ́ tó fọmọọ tiẹ̀ sílẹ̀; Tó wá ń tọ́jú ọmọ ọlọ́mọ. Èèyàn tó fi tiẹ̀ sílẹ̀, Tó ń gbọ́ tẹni ẹlẹ́ni; Ọba-òkè nìkan ní í bá wọn gbọ́ tiwọn. Ișẹ́ pàtàkì nișẹ́ olùkọ́. Ișẹ́ tó lérè púpọ̀ kúkú ní í ṣe. Olùkọ́ lÀnábì ọmọ Àmíná. Olùkọ́ ni Jésù Kírísítì náà. Olódùmarè lolùkọ́ àkọ́kọ́, Ọba tó fìmọ̀ mọ gègé lọ́jọ́ ọjọ́ un. Òun ló fìmọ̀ mọ ẹni tí ò mọ̀ lọ́jọ́sí. Kááábíèsí Ọba tó ju gbogbo ọba lọ. Òun làgbà òpìtàn tó mọ dúníyàn látìpìlẹ̀. Ișẹ́ tÁdániwáyé yọ́nú sí nișẹ́ olùkọ́, Ẹ jẹ́ ká ṣe é bó bá ṣe yẹ. Bẹ́nìkan ò rí wa, Ọba lókè ń wò wá dájúdájú. Bẹ́nìkan ò yẹ̀ wá lọ́wẹ̀ wò, Èdùmàrè kúkú ń rí wa ní kedere. Ișẹ́ àfọkàntán nișẹ́ olùkọ́. Ká tó kọ̀wé ìkọ́ni, Ká tó pète pèròo kíkọ́ni lákọ̀ọ́yé. Ká tó șàlàyé tó yè kooro. Ká tó kọ nóòtì sójúu bọ́ọ̀dù, Ká tó buwọ́ lu ișẹ́ akẹ́kọ̀ọ́. Ká tó șàtòjọ ìbéèrè ìdánwò. Ká tó máàkì, Ká tó gbésì ìdánwò wa sí gbangba. Ẹ wá rí i pé, Ișẹ́ tó lápẹpẹ yéye ní í ṣe. Ọba lókè ló lè șẹ̀san olùkọ́, Ẹ jẹ́ ká kó yẹ̀yẹ́ dànù. Mo dúpẹ́, Orí ṣe mí lólùkọ́. Mo wáyé, Mo lapa lára onírúurú ọmọ. Ișẹ́ tó wù mí bí ișẹ́ à ń mẹ́fun ò sí. Bí mo bá ń wáyé nígbà igba, Olùkọ́ ni n ó yà fáàbàdà. Ẹ kú dédé àsìkò yìí gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí, ẹ fojú sọ́nà fún ẹ̀tò pàtàkì tó ń bọ̀ láìpẹ́ láti ọwọ́ àwọn olùdarí Èdè Yorùbá Rewà. Ìsòkan la fẹ́ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Àlàyé nípa Amúṣan Amúṣan ni ọmọkùnrin tí a bí, tí ó fi àpò rẹ̀ bo orí gẹ́gẹ́ bí eégún. Àwọn olórìṣànlá a máa tọ́ka sí AMÚṢAN gẹ́gẹ́ bí SÀLÀKỌ́. Oríkì Amúṣan Amúṣan ògogó, O r'íbà ọrọ̀! Ògogó òkú kò gb'orí, Onígborí mi l'Ọ́yọ mọ̀kọ. Baba síngín ní ijo awo! Kẹ́kẹ́ ni mo ṣá Tí Mo mú ṣẹ èwe tí Àpínni; Àbàjà ni mo bù, Tí Mo mú ṣẹ èwe tí Àgùrè; Gọ̀mbọ́ ni mo wà, Tí Mo mú ṣẹ èwe tí Ògbórí. Tí Onígborí mi l'Ọ́yọ! Baba wá kí á siré awo! Ògogó, o r'íbà ọrọ̀! Ẹ fojú sọ́nà fún oríkì ọmọbìnrin tí ó fi àpò rẹ̀ bo orí gẹ́gẹ́ bí eégún Ọ̀RỌ̀ ìṣítí fún gbogbo òbí sí ọmọ. Ọ̀RỌ̀ ìṣítí fún gbogbo wa. Ìrántí olóògbé Pẹ̀lú ìwòye tèmi Yorùbá ló maa ń tọju obìnrin Ẹ jẹ́ ká jó ẹ jẹ́ ká yọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pé ọdún MÉJÍDÍNLLỌ́GỌ́TA Ẹ̀bùn ránpé wà fún ẹni tí ó bá gba ÌBÉÈRÈ yìí Ǹjẹ́ ìwọ ṣe irú èyí sí gègé rẹ ayò ọlọ́pọ́n, ǹjẹ́ ìwọ mọ bí wón ti ṣe ń ta ayò yìí Ǹjẹ́ ìwọ ṣe irúfẹ́ ère yìí nígbà èwe rẹ. Dárúkọ ọdún Ẹ jẹ́ kí á tepá mọ́ṣẹ́. Múra síṣẹ́ Ọ̀lẹ́dàrùn wáṣẹ́ ṣe Ẹni tó ń ṣíṣẹ́ lọ́wọ́ ó múra ṣíṣẹ́ Ẹ̀dá tí kò ì rí kó má sọ̀rètí nù Iṣẹ́ takuntakun nii mú Kénìyàn ó le kẹ́sẹ́járí Iṣẹ́ nii múni gbọ́n Àìṣíṣẹ́ níí múni gọ̀ ju taṣutaṣu lọ Ẹni bá ṣíṣẹ́ á lówó lọ́wọ́ Múra ṣíṣẹ́ tó o bá nísẹ́ lápá Tẹra mọ́ṣẹ́ níbi o bá ti ráàyè Ìtẹramọ́ṣẹ́ níí mágbẹ̀ jẹun kánú Ìtẹramọ́ṣẹ́ níí sọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ dọ̀gá Ìtẹramọ́ṣẹ́ níí fágbéga lẹ́nu isẹ́ Ìtẹramọ́ṣẹ́ níí mú màjèsín dé pò àgbà. Kí obìnrin to àtòrìn,Kí Ọkùnrin to àtòrìn,ká wo ẹni tí ó ma lómi léyìn ẹsẹ̀ ju ara wọn lo. Láaláa tó r'òkè , ilè ni ń bọ̀. Mo dàgbà nkọ̀ S'oge mó , owó ni kò sí. Níbití erin méjì bá ti ń jà, koríko ibè kò ní gbé rí mó. Orí tí yóò gbeni ní gbé aláwo ‘re ko ni Ọlọ́pà èwo ni tèpè,amúni ń jẹ́ amúni. Pàṣán ológìnní, kò sí lọ́wọ́ èkúté. Rírò ni t'ènìyàn , ṣíṣe ni ti Ọlọ́run. Sàsà ènìyàn ló ń fẹ́ ni lẹ́yìn bí a ó bá sí ní ilé, t'ẹrú t’ọmọ ló ń fẹ́ ni lójú ẹni. Ṣàkátápàrá làá síntọ́, ojú àfọ́ọ̀fọ́tán, ìjà lón dá sílẹ̀ Tí a bá kì f’awo, awo á kì f’ọ̀gbèri . WÈRÈ dùn wò, kò ṣeé bí Yin ni, yin ni, k’ẹni leè ṣe òmíràn Eré òṣùpá ORÚKỌ tí a ń sọ àti àwọn ìdí tí a fi n sọ wón (orúkọ àmútorúnwá). Èdùmàrè a sọ ìpàdé wa ju ọ̀la lọ. Ní ayé àtijó, ìgbín àti Ìjàpá jọ ń ṣe ọ̀rẹ́. Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ni wọ́n ṣe. Gbogbo ìlú ló sì mọ̀ wọ́n papọ̀ pé ọ̀rẹ́ gidi ni wọ́n ń ṣe. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìwà Ìjàpátìrókò ọkọ yánníbo ọ̀dàlẹ̀ pátápátá ni. Ní ìlú tí ìgbín àti Ìjàpá ń gbé, ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kan. Se ni òkìkí kàn pé ẹnìkan ti pa abukẹ́ Ọba. Ọsìn ni orúkọ oyè Ọba ìlú náà. Bí Ìjàpá tí gbọ́ pé àwọn kan ti pa abukẹ́ Ọsìn, ni ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba láti lọ sọ fún un pé ọ̀rẹ́ òun ìgbín ni o pa abukẹ́ Ọsìn. Ọba bi Ìjàpá bóyá ohun tí ó sọ dáa lójú daadaa à bí eré ló ń ṣe. Ìjàpá sọ fún ọba bí òun àti ìgbín ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn àti bí àwọn kì í ṣe fi nǹkan kan pamọ́ fún ara wọn. Ìjàpá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìgbín fúnra rẹ̀ ló wá sọ fún òun pé òun ni òun pa abuké Ọsìn. Kíá ni Ọba ránṣé pé kí wọ́n ó lọ mú ìgbín wá. Wọ́n mú ní papámọ́ra wá sí ilé Ọba. Nígbà tí wọ́n mú dé ọ̀dọ̀ Ọba, Ọba bi ìgbín léèrè bóyá òun ni ó pa abúlé Ọba. Ìgbín dá Ọba lóhùn pé kì í ṣe òun ni òun pa abuké Ọba àti pé bí Ọba bá fẹ́ mọ ẹni tí ó pa abuké Ọba òun lè ràn Ọba lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ó mọ ẹni tí ó pa á. Nígbàtí Ọba gbọ́ báyìí, ó pàṣẹ pé kí wọ́n tú ìgbín ṣílẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n tú ìgbín sílẹ̀ tán, ó sọ fún Ọba pé láti mọ ẹni tí ó pa abuké Ọba wọ́n ní láti fún òun ní ẹṣin ńlá kan àti àwọn Onílù. Ọ̀rọ̀ yìí kò kọ́kọ́ yé Ọba ṣùgbọ́n nígbà tí ìgbín tí fọwọ́ sọ̀yà pé òun yíò fi ojú ẹni tí ó pa abuké Ọba hàn, Ọba kò Jáà níyàn ó ṣe bí ó ti wí. Ó fún ìgbín ni ẹṣin ńlá kan àti àwọn Onílù. Ìgbín gun orí ẹṣin, o sì ní kí àwọn Onílù ó máa lu ìlù tẹ́lẹ̀ òun báyìí pé: Báyìí ni Ìgbín bẹ̀rẹ̀ sí gun ẹṣin kiri tí ó gun ún yíká gbogbo ìlú. Nígbà tí Ìjàpá gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ inú rẹ̀ bàjé ó ń ronú pé òun ni ó yẹ kí Ọba dá lọ́lá torí òun ni òun pa abuké Ọba. Ìjàpá múra, ó di ilé Ọba. Nígbà tí ó dé ààfin Ọba, ó kí Ọba pẹ̀lú ìdọ̀bálẹ̀, ó sọ fún Ọba pé òun ni ó yẹ kí Ọba dá lọ́lá torí pé òun ni òun pa abuké Ọba. Ọba bíi léèrè bí òun ti ó sọ dáa lójú. O sì tún sọ fún Ọba pé òun ni òun yẹ fún ọlá tí Ọba dá Ìgbín torí pé òun ni òun pa abuké Ọba. Kíá ni Ọba ní kí àwọn ẹmẹ̀wà òun mú Ìjàpá kí wọ́n dìí tapá tẹsẹ̀ kí wọn ó ti ojú rẹ yọ idà, kí wọn sì ti ẹ̀yìn rẹ̀ tí bọ àkọ̀. Báyìí ni Ìjàpá fi ẹ̀tanú àti ìwà ọ̀dàlẹ̀ pa ara rẹ̀ tí Ìgbín sì ń jẹ ayé rẹ̀ lọ níbi tí ó tutù títí di òní yìí. Ìtàn yìí kọ́ wa wípé kò yẹ kí á máa ṣe ìlara ẹnìkejì wa. Mo wq fi àsìkò yìí ro gbogbo àwọn ènìyàn ti ìwà wọn jọ tí Ìjàpá ki wón lọ yí padà. Ẹ jẹ́ ká gbé òsùbà fún Ààrẹ orílè èdè Nàìjíríà Muhammad Buhari fún tí GCFR tí ó fi dá Mashood Kashimawo Olawale(MKO) lọ́lá àti yíya ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹfà (June12) sì ọjọ́ ayẹyẹ ìjọba tiwantiwa. Ìwúrí ńlá ni eléyìí jẹ́ fún gbogbo ọmọ Yorùbá pátápátá Bọ̀dá Màjídì tún gbé tuntun dé óò. Ṣé ó mọ Age mi ni Gba ìbéèrè yìí kí o je Ẹ̀bùn ránpé. ÌLÀNÀ:Ó gbọdọ̀ dáhùn ìbéèrè yìí láti àkókò yìí títí di agogo méje alẹ́ òní Ọ̀RỌ̀ ìṣítí Òwe Yorùbá Kíni ẹ̀yin rí sí ọba Ìwó tí ilè Ìwó tí o yí orúkọ oyè ọba padà sí Emir Ẹsẹ rere Ọ̀rọ̀ Ìkìlọ̀ Ọmọ aráyé ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra fẹ́nu Ẹnu ní í lani Ẹnu ní í pani Ẹnu ní jin ni sọ́fìn Ẹnu làá fi ń tún ènìyàn ṣe Ẹnu la fi ń bá ènìyàn jẹ Ẹnu wa ò ní pa wá Kí o tó fi ẹnu sọ ohunkóhun Ẹ jẹ́ ká ronú jinlẹ̀ Torí bí ọ̀rọ̀ bá ti balẹ̀ Kò ṣe dápadà mọ Wọ́n ni ká bọ eégún ilé A bọ eégún ilé Wọ́n ní ká bọ òrìṣà ọjà A Bọ òrìṣà ọjà Wọ́n ní ká bọ olúbọ̀bọ̀tiribọ̀ baba ẹbọ Ǹjẹ́ kí ni olúbọ̀bọ̀tiribọ̀ baba ẹbọ? Wọ́n ni ẹnu ní i jẹ́ bẹ́ẹ̀ Ǹjẹ́ kí ni wọ́n ní bọ n'ife? Ẹnu ní wọ́n ń bọ n'ife Èdùmàrè ò ní jẹ́ kí ẹnu wá pa wa oooo Orin Ọmọ kékeré ẹnu lẹbọ ooo Ẹnu lẹbọ Àgbàlagbà ẹnu lẹbọ ooo Ẹnu lẹbọ Ẹnu ló wọ́lé e bàbá kan Ẹnu lẹbọ Ó di àrìnàkò, ó dojú àlá Ọ̀jọ̀gbón IGBÓ OLÓDÙMARÈ APÁ KEJÌ ÒGBÓJÚ ỌDẸ NÍNÚ IGBÓ IRÚNMALẸ̀ láti ọwọ́ D. O. FÁGÚNWÀ Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ Ìwé yìí wà fún tọmọdétàgbà lọ́kùnrin lóbìnrin ní ilẹ̀ ènìyàn dúdú, àti pàápàá ní ilẹ̀ Yorùbá, ti wọ́n jẹ́ ìbílẹ tí wọ́n sì mọ èdè Yorùbá a kà dáadáa, àti fún àwọn ilé-ẹkọ́ kékeré pẹ̀lú. Ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí kún fún ọgbọ́n o sì dùn bí oyin. D.O. Fágúnwà Ìfihàn Ìbẹ̀rẹ̀ Olówó-ayé Olówó-ayé lọ sí Igbó Olódùmarè Ìjà ibodè Igbó Olódùmarè Ọdẹ aperin ṣìnà sínú Igbó Olódùmarè: gọngọ sọ Ọjọ́ kejì lọ́dọ̀ baba-Onírùngbọ̀n-Yẹ́úkẹ́ ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta Ọjọ́ kẹta lọ́dọ̀ baba-Onírùngbọ̀n-Yẹ́úkẹ́ ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta Ìpínyà pẹ̀lú baba-Onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta Òjòlá-ìbínú tí i ṣe olórí ejò ayé gbogbo Àlàyé, ìbéèrè ati ìdáhùn Ìbẹ̀rẹ̀ Olówó-ayé Lọ́sàn-án gangan ijọ́sí, nígbà ti mo jẹun ẹ̀ẹ̀kejì tán, mo kúrò ní ilé mi, mo bọ́ si ẹ̀yìn odi, mo gun orí àpáta ńlá kan lọ; nígbà ti mo si dé òkè lọ́hùn-ún tán, mo bọ́ sí abẹ́ igi kan tí ó hù sí orí àpáta, mo jókòó mo lé góngó; bẹ́ẹ̀ ni òòrùn náà mú gidigidi, ara ọmọ aráyé gbóná bí ìkòkò èlùbọ́, òógùn bo ara gbogbo ènìyàn, àfi bí ẹni pé wọ́n bu pmi sí ara ni. Èmi náà bọ́ sọọ ara mi sílẹ̀, àfi ṣòkòtò ló kù sí ìdí mi, èmi tí mo ti dé fìlà ri, tí mo tẹ fìlà mi siwaju kọ̀ǹgọ̀, ṣí fìlà kuro ní àtàrí, atẹ́gùn àlàáfìà sì ń fẹ́ sí ,i ní ìpàkọ́. ọ̀án pọ́n gidigidi; àwọn àgbẹ̀ pàápàá ti sá kúrò nínú oko, wọ́n n rẹ́rìn-ín nínú ahéré; aláàárù kò le sọ̀rọ̀ mọ́, wọ́n ń mi hẹlẹ bí wọ́n ti ń gun orí òkè; ojú ọ̀nà le bí òkúta; gbòǹgbò le bí ìdàrọ́, ilẹ̀ pupa bí epo, etí ṣòkòtò funfun bàjẹ́, etí ẹ̀wù agbádá di pupa; àánú àwọn oní mọ́tò ṣe mí, ara wọn kún fún èéri, ó dà bi ewéko ojú ọ̀nà, àwọn tíó sì jókòó sí ẹhin ọkọ̀, àwọn wọ̀n-ọnnì kun àtíkè ìjàngbọ̀n, wọ́n pupa bi ẹ̀gbẹ́ ògiri, eruku bo ọmọ aráyé gbogbo; ogunlọ́gọ̀ àwọn ẹ̀dá alààyè ni wọ́n mọ̀ pé òòrùn náà mú, àwọn aláǹgbá ń sáré, ara wọn ń dún hánrán-hánrán lórí ewé gbígbẹ; àwọn ẹyẹ ńlá kò sì ké mọ́, nítorí mo ti gbọ́ igbe ẹ̀lúùlu, mo ti gbọ́ ohùn àdàbà, ẹyẹ agbe ti ké, àlùkò ti sọ̀rọ̀, olúkúlùkù wọn sì ti dákẹ́ minimini sí ibi tí Olódùmarè sọ wọ́n lọ́jọ̀ sí, àfi àwọn ẹyẹ kékeré gbogbo tí wọn kò tóbi ju alápàáǹdẹ̀dẹ̀ ni wọ́n ń fò síhìn-ín sọ́hùn-ún, tí ara wọn kò balẹ̀ bí ewé oju omi, wọ́n ń ti orí igi dé orí igi bí wọ́n ti ń ké bí ọmọ adiẹ. Bẹ́ẹ̀ ni èmi rọra jókòó ní tèmi, tí mo ń wo ojú ayé, ti mo ń ronú nípa àwọn ọmọ ènìyàn, nítorí onírúurú ènìyàn ni mo ti bá gbé pọ̀ rí; àkókò ìgbá mo sì ń sọ̀rọ̀ yìí, àkókò pàtàkì ni ó jẹ́ ní ìgbésí-ayé mi, nítorí ìgbà náà ni bàbá mi pa ojú dé, tí ó rékọjá òkè odò, ti ó kí ayé pé ó dìgbòóṣe, tí àkùk��� kọ l’ẹyìn ọkùnrin. Ọ̀ràn náà dùn mí dé inú egungun, nítorí bàbá mi kì rí bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin. Òun àti ìyá mi fẹ́ràn ara wọn, wọ́n sì fi àpẹẹrẹ rere lé ilẹ̀ fún awa ọmọ - èyínì ni èmi, Adéyẹmí, Ojúọlápé, àti Ọmọ́túndé. Réṣẹ́ẹ̀lì Ọ̀ṣúnyọmí tí í ṣe ìyá mi jẹ́ obìnrin tí ó fẹ́ràn baálé rẹ̀ tí ó sì fẹ́ràn ọmọ, ọ̀spọ̀lọpọ̀ àánú ní ń bẹ ihò ojú ìyá mi. Ìyá mi ń bẹ lónìí, ṣùgbọ́n bàbá mi kò sí, ṣùgbọ́n ọ̀ràn ikú bàbá mi dùn mí gidigidi. Nítorí ó ṣe fun mi bí bàbá tí í ṣe fún ọmọ, èmi náà sì sa ipá mi dé góńgó kí òun ba le mọ̀ pé mo mọ ohun tí òun ṣe fún mi, bẹ́ẹ̀ ni onírúurú ǹkan ńlá gbogbo ni mo ń rrò nínú ara mi pé bí bàbá mi kò bá tètè kú, n ó fi wọ́n ṣe bàbá mi lóore. Nítorí bí ènìyǹa tilẹ̀ n wọ ẹ̀wù àkísà, tí olúwaarẹ̀ sì ń da aṣọ aláṣọ bora, ṣùgbọ́n tí olúwaarẹ̀ kò bá gbàgbé àwọn ẹni tí ó bí i, Olódùmarè náà kò ni í gbàgbé òun. Ṣùgbọ́n bí èmi ti ń ronú wọ̀n-nnì, èdè Ẹlẹ́dàá yatọ sí tèmi, bẹ́ẹ̀ni Ẹlẹ́dàá gbọ́n jù mí lọ; ìgbà tí ó sì di òwúrọ̀ ọjọ́ kaan báyìí, wọ́n wi fún mi lati ile pé, bàbá mi ti lọ sí ọ̀run alákeji. Bẹ́ẹ̀ ni ìbànújẹ́ da orí mi kọ odò, tí ara mi gbóná bí ìṣaasùn ori iná, tí inú mi dàrú bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù ba ń fẹ́ igi oko, tí aye sú mi bi àkísà ẹlẹ́gbin, tí ọ̀run sì dára bi wúrà lójú mi. Ìwọ̀nyí ni mo bẹ̀rẹ̀ si í rò ní ọ̀sán gangan ọjọ́ tí mo ń wí yìí, lẹhìn ìgbà tí mo ti kúrò nínú ilé tán, tí mo lé góńgó lórí àpáta. Àṣẹ́ bí èmi ti jókòó wọ̀n-ọnnì, ẹnìkan ń bẹ ní igbó ṣúúrú kan lẹ́bàá ọ̀dọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ ní tèmi, jíjókòó ni mo jókòó tí mo ń wo iwájú, n kò sì eo ibi kọ́lọ́fín tí ó yí mi ká gbogbo. Ìbá ṣe pe mo mọ eléyìí tẹ́lẹ̀ ni, emi ìbá ti tètè kọ orí sí ọ̀nà ibòmíràn, kí n jókòó sí ibi tí ẹnikẹ́ni kò lè rí mi. Nítorí mo ń fẹ́ẹ́ ronú lákòókò náà ni, n kò si fẹ́ ki ènìyàn dí mi lọ́wọ́ rárá, níotrí àkókò iré ni iré yẹ ní ṣíṣe, àkókò ìjà yẹ ní jíjà, àkókò ẹkún ni ẹkún yẹ ní sísun, àkókò ayọ̀ yẹ ní yíyọ̀; ẹni tí o ń lọ sí àwùjọ tí ó dé fìlà ará oko tí ó wọ ẹ̀wù ẹmi tí ń rin ìrìn-àjò, tí ó sì sán ìbàǹtẹ́ ẹni tí ń ṣe ọdẹ, eléyìínì ti gbé kọja oríta, níttorí náà bí èmi ti ń fẹ́ẹ́ ronú lákòókò náà, n kò fẹ kí ẹnikẹ́ni dí mi lọ́wọ́ rárá. Ṣùgbọ́n bí mo fẹ́ bí mo kọ̀ ọkùnrin náà yọ sí mi dandan; inú bí mi gidigidi, mò fa ojú ro bi ẹni tí ebi ń pa, mo ń pòṣé bí ẹni tí iyà ń jẹ, mo di ẹnu dudu bi ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó fọ́ àwo oúnjẹ, tí kò lè sọ fún ni, tí ó rìn káàkiri ẹ̀gbẹ́ ògiri, tí inu ọmọ náà si dàrú bi ìgẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ìdí ẹmu inu ṣágo. Nígbà tí ọkùnrin náà kí mi èmi náà rọra dá a lóhùn ọ jàre, nítorí kí ni ńkọ́? Nítorí kí ọ̀ràn mi má ba dà bí àṣejù, ki wọ́n má ba sọ olúwaarẹ̀ lórúkọ, wọn a si wí pé olúwaarẹ̀ kì í ṣe ọmọlúwàbí, eléyìínì náà ló jẹ́ kí n ṣe ojú ayé ní tèmi, nítorí kíkí tí mo kí i kò ti inú ọkàn mi jáde. Lẹ́hìn tí mo kì i tán mo bẹ̀rẹ̀ sí hùwwà bí ẹni pé kí ó bínú lọ; mo dákẹ́ n kò sọ̀rọ̀, ó sọ̀rọ̀ n kò rẹ̀rìn-ín, mo dìde níbi tí mo lé góńggó sí mo ṣiré lọ sí ìsàlẹ̀ àpáta, bẹ́ẹ̀ ni n kò tilẹ̀ wí fún un kí n tóó dìde, n kò tọro gááfárà lọ́wọ́ rẹ̀, bí ó ti yẹ kí n ṣe, nígbà ti mo si tún padà dé, mo bá a níbi tí mo fi í sí i mo sì tún rọra jókòó ní tèmi láìjẹ́ mo kí í, láìjẹ́ pé mo fọhùn sí i, láìjẹ́ pé mo tilẹ̀ wò ó lójú rárá, mo ń kọ̀rin, mo ń súfèé, n kò sì wí pé kí ó jókòó. Ṣùgbọ́n èyí tí ó tilẹ̀ wáá dùn mí ni pé ṣe ni mo rí ọkùnrin náà ti ó fi ìdí lé àpáta tí ó tun fi ara mọ́ mi tímọ́tímọ́ bí ìgbà tí ọmọdé fi ara mọ́ abiyamọ, mo ní ǹkan parí náa wwàyí, ìjàngbọ̀n lé mi kúrò ninu ilé mo bá ìjàngbọ̀n lórí àpáta, mo bu òkèlè kọjá ibi ti ẹnu mi gbà, mo fi omi tútù ro èlùbọ́, mo fi àkàrà jẹ ìrẹsì, mo gbé gaàrí fún òyìnbó wà mu. Ibi tí mo ti ń ronu báyìí ni ọkùnrin náà ti kígbe láìròtẹ́lẹ̀, ohùn rẹ̀ sí dà bí ìgbà tí jàgídíjàgan ìranńṣẹ́ bá da ǹkan lulẹ̀ láti ibi gíga; ẹrù bá mi bí ìyàwó ẹni tí ó lọ sí ojúu ogun, mo sì ń wárìrì bi ìgbà tí alùpùpù tí ó bàjẹ́ bá ń gun orí òkè, níotrí igbe ọkùnrin náà lágbára bi ti kìnnìún, ó rin ilẹ̀ dòdò bi ti àjànàkú ó gba igbó kankan bí ìgbà tí rélùwéè bá ń súnmọ́ etí ìlú tí ó ń fún fèèrèkikankikan. Akókò yìí ni mo tóó wáá wo ọ̀gbẹ́nni náà dáradára, ìyàlẹ́nu ló si jẹ́ nígbà tí mo rí i pé ọ̀rẹ́ mi ayé àtijọ́ ni, ọkùnrin mẹ́ta, àkàrà-oògùn, a-bá-olóúnjẹ-kú, ẹni tí ó bá àgbákò jà nínú igbó Irúnmalẹ̀, ẹni tí ó rin ìrìn-àjò ti Òkè Láńgbòdó bọ̀, ẹni tí ó wá si ilé mi ní ijọ́sí, ti irohin náà si gba gbogbo orílẹ̀-èdè yí kankan. Òun wò mí ó bú si ẹ̀rin, emi náà sì wò ó ẹ̀rín ti ẹ́nu èmi náà jáde. A múra a kí ara wa; kò sì dàgbà ju ti àtijọ́ lójú mi, ṣùgbọ́n ìbọn ọkùnrin náà túbọ̀ dúdú sí i, ó da bí aṣọ kíjìpá àgbàlagbà obìnrin, tí wọ́n ti rà kí ìyá mi tó wọ ile ọkọ, ti wọ́n sì ti pa ní aró ní oríṣiríṣí ìgbà, ti kíjìpá eléyìínì dúdú kẹlẹkẹlẹ, bẹ́ẹ̀ ni fìlà àkàrà – oògùn a máa wù mí, nítorí ìgbà tí òun bá kó ìṣáná àti ewé tábà sí inú rẹ̀ tán, tí òun bá si tẹ fìlà náà sí ìpàkọ́, eléyìínì a da bi èèso orí igi. Ìgbà tí ó bá si ń kọjá nígbà míràn tí ó bá tẹ fìlà náà siwájú kọ̀ǹgọ̀, eléyìínì a dà bí ìdí ọ̀pá ìtìlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni bí ó bá ń ṣe fáàrí nígbà míràn, òun a tẹ fìlà yí sí ẹ̀bá etí, eléyìínì a sì dà bí akèǹgbà orí ọ̀pẹ. Mo dáhùn mo sì wí pé: “Àkàrà-oògùn,” òun náà fèsì ó ní, “Èmi náà nù-un.” Mo sì tún pè é lẹ́ẹ̀kejì mo ní, “Àkàrà-oògùn,” òun náà si tún fèsì ó wí pé, “Bẹ́ẹ̀ náà ni, máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ.” Mo tún pè é lẹ́ẹ̀kẹta pẹ̀lú mo wí pé, Àkàrà-oògùn, òun náà sí ẹ̀rín, ó fi ọwọ́ sọ àyá, ó wí tìgbéragatìgbéraga, ó ní, ‘Àkàrà-oògùn ni orúkọ mi, orúkọ ńlá ni mo ń jẹ́, oríkì ti ó rọ̀ mí lọ́rùn ni mo gbà, ìrìn ẹsẹ̀ tí ó yẹ mi ni mo ń rìn kiri, èmi ni ọ̀rẹ́ rẹ àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni agbára mi kò dínkù, egungun ń bẹ lára okùnrin; ki ọwọ́ bọ àpò rẹ, bóyá ohun ìkọ̀wé le wà níbẹ̀, gọngọ á sọ lónìí; mo ní iṣẹ́ láti rán ọ si àwọn ọmọ aráyé, nítorí ọ̀rọ̀ pàtàkì ń bẹ ní agbárí, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn tí ó níláárí ń bẹ ní àtàrí mi, nítorí náà mo fi orúkọ àwọnn ènìyàn dúdú bẹ̀ ọ́, jọ́wọ́ dọ̀bálẹ̀ lórí àpáta, kí á fi àpáta ṣe tábìlì wa, kí èmi dúró gẹ́gẹ́ bí alága, kí ìwọ dúró gẹ́gẹ́ bí akọ́wé, kí ewéko igbó sì dúró gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ fún wa. Nígbà tí ó wí eléyìí, inu mi dùn bí inú ẹni tí wọ́n pè lẹ́jọ́ ẹ̀wọ̀n ṣùgbọ́n tí adájọ́ dá láre, nítorí mo rí ohun tí mo ń wá, mo ṣe alábàápàdé ohun tí ó wù mí, Olódùmarè fi bọ́tà sí búrẹ́dì fún mi; mo ki ọwọ́ bọ àpò nítòótọ́, mo sì rí ohun ìkọ̀wé kítikìti, mo bá dọ̀bálẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ si bá iṣẹ́ ọwọ́ lọ. Àkàrà-oògùn báà rora fi ìdí lé orí àpáta ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ bi oódẹ, ó ní:- Àkàrà-oògùn ni mí nítòótọ́, oníṣègùn ni bàbá tí ó bí mi í ṣe, babaláwo sì ni pẹlu, oògùn kún inú ilé wa dé ẹnu, bẹ́ẹ̀ ni nǹkan abàmì ń bẹ ní kọ̀rọ̀ iyàrá, egbòogi ńlá ń bẹ lóké àjà, onírúurú ohun alááyyè ní si ń bẹ ní àgbàlá wa. Ẹni tí ó ní wárápá bàbá mi wo wárápá fún un, ẹni tí ó ní sòbìyà bàbá mi wo sòbìyà rẹ̀ sàn, ọ̀kẹ́ àìmoye àwọn adẹ́tẹ̀ ni òun sì sọ di gbajúmọ̀ nínúu ilé wa. Bàbá mi fi ìyà jẹ ṣànpọ̀nná; ó fi àbùkù kan òè-ilẹ̀: ó ba làkúrègbé lórúkọ jẹ́; inúrírun di èrò ẹ̀hìn; orí-fífọ́ di ẹni kékeré: ẹ̀hìn-dídùn kò le sọ̀rọ̀; ikọ́ ti sápamọ́; aràn àyà bá ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀; jẹ̀díjẹ̀dí dákẹ́ mini-mini; ibà ń rìn tìrònù-tìrònù; ìgbẹ́ ọ̀rìn doríkodò; kúrúnà ń sọkún;egbò ń pòṣé; ifọ̀n fa ojú ro, otútù si ń káàánú. Asínwín obínrin ń ṣe fáàrí; wèrè ọkùnrin ń fá irùngbọ̀n; aboyún ń bímọ pẹ̀lú àǹfààní; abiyamọ ń rìn tayọ̀-tayọ̀; àwọn oṣó ń túúbá, àwọn àjẹ́ ń tọrọ àforíjì. Àwọn ẹlẹ́bọlóògùn sì ń foríbalẹ̀ níwájú bàbá mi. Ìwọ ọ̀rẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ fún ọ ni ijọ́ sí ògbólógbòó àjẹ́ ni ìyá mi. Òun a máa fò lọ́sàn-án, òun a má fò lóru, òun a si máa fi agbárí ènìyàn mu omi. Ìy�� mi ti fi apá ọmọdé jẹ̀ àkàṣù ẹ̀kọ, òun ti fi ẹesẹ̀ àgbàlagbà jẹ ìrẹsì, òun si ti fi párì ẹ̀rẹ̀kẹ́ géńdé wa gàrí mu. Ìtàn bí bàbá mi ti ṣe fẹ́ ìyá mi yẹ ní sísọ, nítorí n kò tí ì sọ eléyìínì fún ọ rí, bẹ́ẹ̀ ni ìtàn dídùn náà ni, kò sí nǹkankan nípa ìgbásí-ayé bàbá mi tí n kò mọ̀, nítorí òun náà pàápàá kò jáfàra nígbà tí ó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé, bí bàbá mi ti sun iṣu sí iná bẹ́ẹ̀ bi o ń fi ojú w;a ọ̀bẹ, bí ó ti wà ní ayé nígbà náà a máa tẹ ọ̀rọ̀ yìí mọ́ wa létí nígbàkúùgbà pé, ‘Ọkùnrin tí ó jí ní kùtùkùtù ọjọ́ ayé rẹ̀ tí ó gbé ọ̀ràn obìnrin lé ibi pàtàkì oókan àyà rrẹ̀ kò ní í di pàtàkì láéláé; obìnrin tí ó jí ni kùtùkùtù tí ó gbé ọ̀ràn ọkùnrin le ibi pàtàkì oókan àyà rẹ̀ kò ní í di pàtàkì láéláé; ọkùnrin tí o tó àkókò àti ní obìnrin ti ó gbé ọ̀ràn obìnrin rẹ̀ ti ó ní lé ibi pàttàkì oókan àyà rẹ̀ yóó di pàtàkì láéláé; obìnrin tí ó tó àkókò àti ni ọkọ tí ó gbé ọ̀ràn ọkọ rẹ̀ tí ó ni lé ibi pàtàkì oókan àyà rẹ̀ yóó di pàtàkì láéláé; ọkùnrin alábòsí tí ó fẹ alábòsí obǹirin tí ó gbé ọ̀ràn alábòsí náà lé ibi pàtàkì oókan àyà rẹ̀ kò ní í di pàtàkì láéláé; obìnrin alábòsí tí ó fẹ́ alábòsí ọkùnrin tí ó gbé ọ̀ràn alábòsí náà lé ibi pàtàkì oókan àyà rẹ̀ kò ni í di pàtàkì láéláé; ọkùnrin pàtàkì tí ó fẹ́ alábòsí obìnrin tí kò gbé ọ̀ràn alábòsí náà lé ibi pàtàkì oókan àyà rẹ̀ yóó di pàtàkì láéláé; obìnrin pàtàkì tí ó fẹ́ alábòsí ọkùnrin tí kò gbé ọ̀ràn aláòsí náà lé ibi pàtàkì oókan àyà rẹ̀ yóó di pàtàkì láéláé, ẹnikẹ́ni pàtàkì ti ó gbe ọ̀ràn ẹlòmíràn pàtàkì lé ibi pàtàkì oókan àyà rẹ̀ yóó di pàtàkì láéláé.’ Bẹ́ẹ̀ ni bàbá mi máa ń sọ fún wa ígbà tí a wà ní èwe, nígbà tí a bá jókòó sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀ tí a ba ń bá ṣiré, bi mo sì ti n ssọ̀rọ̀ yìí, ìwọ ọ̀rẹ́ mi, diẹ ló kù ki omi bọ́ lójú mi nítorí mo rántí bàbá mi Olówó-ayé, arẹwà kọ́kùnrin. Ṣùgbọ́n ó di ọ̀laa kí n tóó máa bá ìtàn bàbá mi lọ, ìtàn ti mo sọ fún ọ ní ijọ́sí tí ìwọ kọ sílẹ̀ fún àwọn ọmọ aráyé wọ̀n-ọ́nnì, ìtàn ara mi ni gbogbo wọn, ọ̀rọ̀ díẹ̀ péré ni mo sì sọ nípa bàbá mi, nítorí náà, iwọ ọ̀rẹ́ mi, máa dìde, dìde kuro ní orí àpáta, níbi tí o da àyà dé ilẹ sí, máṣe jẹ́ kí àyà kí ó dùn ọ́, mo mọ ilé rẹ, mo ń bọ̀ wáá kí ọ lọ́la. Ìgbà tí mo bá dé ni n óò tóó tún máa bá ìtàn bàbá mi lọ. Ó dọ̀la o, kí Ọlọ́run jẹ́ kí a fi ire pàdé lọ́la.’ Báyìí ni ọkùnrin sọ, n kò sì rí i mọ́. Wéré èmi náà dìde lórí àpáta mo bá ilé lọ. Lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì, lẹ́yìn tí mo fi mọ́ínmọ́ín mu ẹ̀kọ àgbàdo tútú tán, tí mo jókòó ní tèmi ni mo rí Àkàrà-òògùn tí ó yọ sí mi gbùlà bí ẹbọra. Ó tún tẹ fìlà rẹ̀ síwájú bí ó ti máa ń ṣe, fìlà rẹ̀ ri kọ̀ǹgọ̀ bí ẹnu ẹyẹ. OLÓWÓ-AYÉ LỌ SÍ IGBÓ OLÓDÙMARÈ Ìgbà tí mo ti rí àkàrà-oògùn ni mo ti mọ̀ pé iṣẹ́ ńlá bẹ̀rẹ̀, mo kọjú sí ìyàwó mi, mo ni, “ Ìyàwó mi ò, n ǹkan dé” òun náà si dá mi lóhùn ó ní ‘Nǹkan kan kò dé baálé mi, múra sí i, Ọlọ́run ọba náà yóó sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Mo mọ̀ pé iṣẹ́ rẹ pọ̀ ṣùgbọ́n ṣíse ni iṣẹ́, n ó tọ́jú ilé rẹ, n ó tọ́jú ọmọ, n ó sì wá oúnjẹ pàtàkì aí ọ ní ọ̀nà ọ̀fun.’ Ìgbà tí ìyàwó mi wí báyìí tán emi náà dá a lóhùn mo ni, ‘mo dúpẹ̀ lọ́wọ́ rẹ fún ìmọ̀ràn ńlá yìí, mo mọ tìrẹ bẹ́ẹ̀, n ó máa bá iṣẹ́ lọ, èmi ọkùnrin ni mo wí bẹ́ẹ̀, ìwọ máa ṣiṣẹ́ rẹ lọ, kí emi náà máa ṣe tàmi, ọkùnrin ń bẹ lára mi, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin ń bẹ lára rẹ, a ó fi ìgbàdùn ilé wa hàn fún àlejò wa.’ Alágbára ni iyì lójú àwọn ọmọ ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ọkùnrin òtúbáńtẹ́ ènìyàn ni lójú àwọn obìnrin – mo wọlé mo kó ohun ìkọ̀wé jo, mo gbàga mo jókòó ti tábìlì mo sì gbé àga kan si ẹ̀bá tábìlì náà lórí eléyìí sì ni ọ̀rẹ́ mi náà jókòó lé, àkàrà-òògùn, a-bá-olóúnjẹ-kú. Àkàrà-òògùn bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ í dọ. Ó ní: “Ìwọ ọ̀rẹ́ mi, nígbà tí ó di ọdún kẹẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ti bàbá mi ti dé inú ayé ni ó múra ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan báyìí tí ó bá igbó àbàmì kan lọ lẹ́bàá ìlú wa láti lọ ṣe ọdẹ,àwọn ara ìlú wa a máa pe ni igbó Olódùmarè, nítorí ibi tí ó ní ẹ̀rù gidigidi ni. Àwọn ọdẹ pàápàá bẹ̀rù Igbó Olódùmarè ju Igbó Irúnmọlẹ̀ lọ, òfin gan-an sì ni ní ìlú wa pé odẹ tí kò bá tí dí ọdẹ aperin kò gbọdọ̀ lọ sí ibẹ̀ lọ ṣe ọdẹ, nítorí ibẹ̀ ni ibúgbé ìyanu – ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ ti ń fọhùn ènìyàn, tí àwọn ẹranko ń ta ọjà fún ara wọn; tí ogunlọ́gọ̀ igi kò ni gbòǹgbò síbẹ̀síbẹ̀ tá ara wọn tutù nini tí ewé wọn sì dúdú mirinmirin. Èkúté t;obi ju òk;et;e, ìgbín si tóbi ju ìjàpá, nínú Igbó Olódùmarè. Àwọn ẹbọra alágbára àti àwọn jàgídíjàgan àǹjànnú ni wọ́n si ń jùmọ̀ ṣe ọ̀rẹ́ pọ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ejò alákọrí gbogbo a tun máa dẹ́rùba àwọn ọdẹ nítorí ibẹ̀ ni ilé olórí ejò ayé gbogbo, Ojòlá-ìbínú ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́. Kí bàbá mi tóó kúrò ní ilé ó pa itú ọdẹ: nítorí ogunlọ́gọ̀ onńdé ni òun sán mọ́ ìbàdí, ọmo ìka ọwọ́ rẹ sì kún fún òrùka àwọn àgbàlagbà bẹ́ẹ̀ ni mààlúù mẹ́fà ni ó fi ṣe sàráà nínú ilé wa. Bàbá mi pe àwọn oníṣègùn ìlú wa jọ ó wá oúnjẹ fún gbogbo wọn, bẹ́ẹ̀ ni egbòogi àtìrandíran sì kún ilẹ̀ wa kítikìti; fún odidi oṣù mẹ́fà ni òun fi ń sá kiri nítorí ọ̀ràn Igbó Olódùmarè yí nítorí ẹni tí ó bá lọ kì í padà bọ̀, wọn a máa ti ọwọ́ ẹbọra dé ọwọ́ ẹbọra. Háà! Aláapọn ni bàbá mi í ṣe, ọkùnrin ju ọkùnrin lọ, Olówó-ayé pọ̀ lọ́kùnrin, ni ọjọ́ tí bàbá mi múra igbó ọdẹ yìí tán, tí o di àti pínyà pẹ̀lú àwọn ìbátan gbogbo, gọngọ sọ ní ilé wa: àwọn oníṣègùn péjọ sí yàrá àwwọn ọdẹ aperin péjọ sí ọ̀ọ̀dẹ̀m àwọn ọmọdé sá gun òkè àjà lọ, onírúurú ènìyàn ni ń bẹ lẹ́hìn kùlé, ewúrẹ́ sáré ewúrẹ́ kọjá ìloro, obìnrin ń sọkún, ọkùnrin ń sọkún, gbájúmọ̀ kò le sọ̀rọ̀, bọ̀ọ̀kìnní fajúro. Ṣùgbọ́n bàbá mi múra bí jagunjagun ìlú Òyìnbó, ó di oògùn mọ́ra bi babaláwo, ó ń rìn bi ẹ̀ni ti ń lọ ìjàkadì, ó sì dúró bi ìgbà tí àwọn ọlọ́pàá bá dúró níwájú olórí wọn. Nígbà tí ó di àkókò àtilọ gan-an, ó pe gbogbo ilé jọm ó sọ̀rọ̀ fún wọn ó wí pé: Ọjọ́ náà pé lónìí wàyí, ti n ó lọ si ibi tí àwọn alágbára ń lọ, sí ibùgbé àwọn abàmì ẹ̀dá, sí ibi ti ó ṣókùnkùn dudu lójú mi, n ó fi àlàáfíà sílẹ̀ lẹhin, n ó wọlé tọ ijàngbọ̀n lọ, ṣùgbọ́n ìṣòro ni bàbá ìṣúra, orúkọ rere dára ju ìyàwó tuntun, bí mo bá fi ara da iṣòro ti òní, n ó rí ìṣúra ti ẹhin ọ̀la, bí mo bá ti igbó Olódùmarè dé tayọ̀tayọ̀, orúkọ mi yóò pẹ láyé gidigidi. Ẹ̀yin ènìyàn mi gbogbo, ẹ má ṣe pa èrò kékeré fún ara yin láéláé, ẹ máa lépa nǹkan tí ó tóbi, ẹni tí ó lepa nǹkan ńlá tí kò le bá ǹkan ńlá olúwarẹ̀ yóò bá ǹkan tí ó súnmọ́ nǹkan ńlá, ṣùgbọ́n ẹni tí ó lépa nǹkan kékeré kò ní í lè duró ní awùjọ àwọn alágbára. Ẹni ti ó gbàdúrà dàńdógò mẹ́wàá bí olúwaarẹ̀ kò ni dàńdóógó mẹ́wàá yóó ni dàńdógó mẹ́jọ, ẹni ti ó ń gbadura ṣòkòtò mẹ́fà bí olúwaarẹ̀ kò ní ṣòkòtò mẹ̀fà yóó ní ṣòkòtò márùn-ún, ṣùgbọ́n ẹni ti ó tọrọ ṣòkòtò kan lọ́wọ́ Olódùmarè, bi eléyìínì bá ni méjì ó yẹ ki ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Ọba. Lóòótọ́ ni mo rí pé gbogbo yín ni ó fajúro, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi le koko bí òkúta dídán inú omi, ìlọsíwájú jìnná sí oníyèméjì, n kò si ṣiyèméjì bí mo ti ń lọ, lágbára Ọlọ̀run Ọba tí ó dá mi n ó padà dé ilé dandan. Oníyèméjì ń ronú ikú sí ara rẹ̀ lówùúrọ̀ òun sì kí lọ́sàn-án bẹ́ẹ̀ ni òun ìbá gbé ọjọ́ mẹ́ta ní inú ayé sí i, ọkàn ẹni ni àlùfáà ẹni. Ẹ jẹ́ kí n máa lọ́, ẹ kí ará ilé gbogbo, ẹ tún ẹ̀yìn mi ṣe, ọkùnrin ń lọ, ẹ bá mi kéde fún gbogbo àwọn ènìyàn pé alágbára lọ bí alágbára sí ibi tí àwọn alágbára ń lọ, ènìyàn pàtàkì lọ bí ènìyàn pàtàkì sí ibi tí àwọn ènìyàn pàtàkì ń rè, kí tọmọdé-tàgbà bọ̀ọ̀kìnní máṣe wí pé èrò igbó Olódùmarè kò ni í bọ̀ mọ́, kí gbogbo àwọn ọmọlúwàbí inu ayé si máa ṣe ìrètí eégúnlẹ́gi.’ Bẹ́ẹ̀ ni Olówó-ayé sọ tí ó fi orí lé ọ̀nà Igbó Olódùmarè, ojú rẹ̀ si ti yípadà, ó ń pọ́n kankan. Ibi tí ó tilẹ̀ ti ń kánjú díẹ̀ ló kù kí ó gbàgbé egbòogi pàtàkì kan báyìí tí ń bẹ nínú àdó, bẹ́ẹ̀ ni bí kò bá mú eléyìínì lọ́wọ́ àtimọ ọ̀nà igbó náà yóò jẹ́ ìṣòro. Iyẹ́ agbe, iyẹ àlùkò, ìyẹ́ àkàlà, atí ìkóódẹ ni wọ́n ffi dí àdó náà lẹnu, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ gbogbo ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, bàbá ńlá wa tí mo sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni ẹni kìíní tí ó kọ́ ṣe ọdẹ ninú Igbó Irúnmalẹ̀ jákèjádòìlú wa, ìgbà náà ni ó sì ti pa erè tí mo ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí tí olúwaarẹ̀ sì dárúkọ ibi tí òun ń lọ wéré ni atẹ́gùn yóò fẹ́ àwọn ìyẹ́ wọ́n-ọnnì wwọ́n ó si dojukọ ọ̀nà ibẹ̀ gan-an; wò mí ọ̀rẹ́ mi, bí kò ṣe pé mo gbàgbé àwọn ọfọ̀ náà ni, èmi ìbá kọ́ ọ, nítorí kò ju gbólóhùn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n péré lọ. Bí n bá tilẹ̀ kọ́ ọ tán èmi ìbá wa àdó náà fún ọ. Igbó Olódùmarè jìnnà gidigidi, ó to ìrìn ọjọ́ méjì gbáko sí ìlú wa. Àwọn aginjù ńlá mìíràn ń bẹ lójú ọ̀nà, bẹ́ẹ̀ náà si ni àwọn odò tí ó tóbi gbogbo, tí wọ́n ń ṣàn tì wọ́n si ń pariwo ńlá bi wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ lórí àpáta. Onírúurú ewéko ni ó wà lójú ọ̀nà, àti èyí tí ó dára àti èyí ti kò dára, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún ni wọ́n sì ń dí ènìyàn lọ́nà bí ènìyàn bá ti ń kọjá lọ bẹ́ẹ̀ ni àwọn alákọrí ìpàǹtí gbogbo ni wọ́n ń dìmọ̀mlù pẹ̀lú àwọn oníjàngbọ̀n itàkùn ti wọ́n ń lọ́ mọ́ onírúurú igi, àwọn ẹranko pàápàá kò tilẹ̀ jẹ́ kí ènìyàn simi, àwọn ìjímèrè àti ìnàkí àti àwọn ọ̀bọ tí ìrù wọn gùn gbọ̀ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń ti orí igi dé orí igi, ojú wọn sì fi ara wé ti ènìyàn bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọmọ ìka ọwọ́ wọn. Lóòótọ́ ọ̀bọ jọ ènìyàn púpọ̀, ó da bi ẹni pé Ẹlẹ́dàá fi wọ́n ṣe ìbátan ara wọn ni. Onírúurú ǹkan ní ń bẹ ní aginjù. Igi tí ó tóbí àti ọ̀pẹ tí ó ga pẹ̀lú àfòmọ́ ara wọn pọ̀ gidigidi, àwọn ẹranko mìíràn sì ń gbé orí ọ̀pẹ tí ó tóbi; àwọn ẹyẹ tí ẹnu wọ́n rí ṣóńṣó kò jẹ fi ọrùn ọ̀pẹ siré nítorí kí wọn má ba pa àdánù àtiri ẹyìn ọ̀pẹ jẹ, ọ̀kẹ́rẹ́ kì í fẹ́ẹ́ pínyà pẹ̀lú ìtàkùn, àwọn ejò tẹ́ẹ̀rẹ́ a máa wá ibi kọ́lọ́fin kiri, ejò ọká ń ba búrúbú’r lábẹ̀ koríko, òjòlà ń gbé etí odò, bẹ́ẹ̀ ni ogunlọ́gọ̀ ejò olóró kò jẹ́ fi inú ihò ṣirè; ìgbín fẹ́ràn ibi tútù, ìjàpá fẹ́ ìtí, ẹ̀lúùlu ń fò lágbeedeméjì, ṣùgbọ́n àdàbà ń káàkiri ibi gíga, ẹyẹ náà sì dúró bí àkùkọ inú aginjù tí ń ràn àwọn ọdẹ létí àkókò; àwọn igi tí ó ti wó lulẹ̀ láti ọjọ́ tí í ti pẹ́ kò lágbára mọ́, olú ń hù lára wọn; ojú ọ̀nà àwọn ẹrnako yàtọ̀ sí ara won, ojú ọ̀nà èekúté rí tẹ́ẹ́rẹ́ ó si ń dán kooro, ṣùgbọ́n ojú ọ̀nà ìmàdò gbòòrò púpọ̀, ó rí gbẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀-gbẹrẹgẹdẹ. Ìwọ ọ̀rẹ́ mi, irohin kò tó àfojúbà, ìwọ náà mọ onírúurú ìṣòro ti ń bẹ ní inu aginjù bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ìyọnu wọ̀n-ọnnì ni bàbá mi fi ojú rí bí òun ti ń bá ọ̀nà Igbó Olódùmarè lọ; síbẹ̀síẹ̀, èmi ni mo wí fún ọ, nǹkan ti mo kà silẹ wọ̀n-ọnnì kò jámọ́ nkankan rárá bí a bá fi wọ́n wé ohun tí ojú rẹ̀ ri nígbà tí ó de ọ̀hún tán- Bàbá mi sùn lójú ọ̀nà ni ọjọ́ kìíní tí ó kúrò ni ilé, nígbà tí ó sì máa di ọ̀sán ọjọ́ kejì díẹ̀ ló kù kí ó dé ibi tí ó ń lọ. Ìgbà tí ó tó déédéé agogo mẹ́ta ni bàbá mi dé igbó tí ó kángun sí igbó Olódùmarè gan-an, orúkọ igbó náà a si máa jẹ́ Aginjù Ìdákẹ́rọ́rọ́: nítorí ibẹ̀ ni ó dákẹ́ jùlọ ni gbogbo abẹ̀ ọ̀run. Iwin kan ṣoṣo ní ń bẹ ní inú igbó yìí, ò gbóna ju àpáàrà ojú ọ̀run.iwin náà kì í jẹ́ kí ẹnikẹ́ni dé igbó Olódùmarè, a máa fún àwọn ọdẹ ní làálàá ṣe, bẹ́ẹ̀ ni òun kò ga ju ẹsẹ̀ bàtà méjì lọ, inú òkìtì ọ̀gán ni òun sì ń gbé. Ẹbọra kúkúrú bìlísì ni, a máa gbé ẹrù pàṣán kiri ọjọ́ ayé gbogbo. Nígbà tí bàbá mi dé igbó yìí, ohun gbogbo dákẹ́ pátápátá, àwọn ewé igi gbogbo doríkodò, ọ̀kan kò sì lu èkejì, bí ẹni pé kò tilẹ̀ si ẹ̀fúùfù rárá ni; àwọn ẹka igi gbogbo sì dúró ṣanṣan bi ìgbà tí jagunjagun bá dúróníwájú ọ̀gá rẹ̀, àwọn ìtàkùn dà bí olókùnrùn níbi ti wọ́n kájọ si, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko ti kọ ibẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ibùgbé wọn; àwọn ẹyẹ ti bá ibi gbogbo ti wọ́n rí lọ, àwọn ohun alààyè sì da bi ìgbà ti onígbèsè bá ń ronú gbèsè rẹ̀, gbogbo igbó dákẹ́ minimini bí ìgbà tí ọ̀fọ̀ pàtàkì bá ṣẹ ènìyàn ti ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ dákẹ́ minimini. Wò mi, ọ̀rẹ̀ mi, níwọ̀n ìgbà tí ó sì ti jẹ́ pé bàbá mi nìkan ni ó kù pẹ̀lú ẹbọra kékeré inú ọ̀gán sí igbó burúkú yìí ńkọ́, àtikọjá bàbá mi kò ní ṣàì jẹ́ ìṣporo. Lẹ́hin ìgbà tí bàbá mi si ti bá ìrìnkèrindò rẹ̀ kiri fún ìgbà díẹ̀ nínú aginjù ńlá yìí tán òun àti ẹbọra kékeré inú ọ̀gàn fi ojú gán-ánní ara wọn. Ọjọ́ ńlá sì ni ọjọ́ náà, nígbà tí àwọn méjèèjì fi ojú gán-ánní ara wọn, ìjàǹbá pàdé ìjàngbọ̀n, ṣìgìdì pàdé àǹjànnú, kìnnìún méjì fi ojú rí ara wọn. Orúkọ ẹbọra yìí ni Èṣù-kékeré-òde. Kò wọ ẹ̀wù bẹ́l ni kò wọ ṣòkòtò, kò dé fìlà bẹ́ẹ̀ ni kò ssán ìbàǹtẹ́, ewé ni alákọrí fi ń bo àṣírí ìdí kiri, ojú kan ṣoṣo ni òun ní, eléyìí sì gún rébété bí òṣùpá títòbi, Èṣù-kékeré kò ní imú rárá, níotrí ojú ti tóbi rékọjà ibi tí ojú mọ, ẹnu rẹ̀ sì gbòòrò bi ibú àtẹ́lewọ́, eyin ẹnu rẹ̀ dàbí ti kìnnìún bẹ́ẹ̀ ni àwọn eyín wọ̀n-ọnnì pupa bi ìgbà tí kìnnìún bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ ẹran tútù tán. Irun bo iwin náà lára bí aṣọ, gbogbo ara rẹ̀ sì dàbí ara ajá ìlú Òyìnbó, bẹ́ẹ̀ ni òṣú bàràkàtà kan ń bẹ ní àtàrí rẹ̀. Bí òun ti gbe ẹrù pàṣán lée èjìká bẹ́l náà ni àpò ńlá kan ń bẹ ni ọrùn rẹ̀tí ó ba ni lẹ́rù gidigidi. Ẹ̀jẹ̀ bo àpò náà bámúbámú, ihùúhù ẹyẹ sì lẹ̀ mọ́ ẹ̀jẹ̀ wọ̀n-ọnnì lára bẹ́ẹ̀ ni oní rúurú òògùn ni wọ́n so mọ́ ọn ni ẹ̀gbẹ́; àdó àti atọ́, egungun ejò àti ìkó oódẹ, ìyẹ́ agbe àti ìyẹ́ àlùkò, pẹ̀lú ẹyọ owọ ayé àtijọ́, àti onírúurú ìwo ẹranko, àti kékeré àti títóbi, àti ìwo àgbọ̀nrín tí ń ká ilá jẹ nínú oko, pẹ̀lú ìyẹ́ àparò tí ń rìn kiri ní inú aginjù, gbogbo àwọn wọ̀nyí péjọ bámúbámú sí ara àoò ńlá ẹbọra kékeré inú ọ̀gán, orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Èsù-kékeré-òde. Bí òun ti ń bọ̀ ni ẹesẹ̀ rẹ̀ ń dún jinwinjinwin nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkaraun ìgbín ni wọ́n gé wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, tí etí ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ri kiribiti bi etí owó ṣílè, ti wọ́n sì fi okùn so gbogbo wọn pọ̀ ìlẹ̀kẹ̀; tí ẹbọra náà tò wọ̀nyí láti ọrùn ẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé orúnkún koko; bẹ́ẹ̀ ni òrùka irin tí ó dúdú bí ọmọ ìka ọwọ́ ìyá aláró ni òun tò si ọwọ́ rẹ̀ gbogbo. Háà! Èmi ni mo wí fún ọ, iwin búburú ni ẹbọra kékeré inu ọ̀gán, orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Èṣù-kékeré-òde. Nígbà ti bàbá mi yọ ìhà ìhín, ti òun náà yọ ní ìhà ọ̀hún àwọn méjéèjì dúró wọ́n ń wo ara wọn: nítorí nígbà ti àjànàkú bá pàdé àjanàkú dandan ni kí igi máa wó lu ara wọn. Òun ń rìn bọ̀, bàbá mi náà ń rìn lọ, ìgbà tí ó si kù díẹ̀ kí wọn pàdé, àwọn méjéèjì tún dúró wọ́n ń wo ara wọn – gọngọ máa sọ. Èṣù-kékeré ni ó kọ́ sọ̀rọ̀ ó la ẹnu rẹ̀ ńlá nì ó sì wí pé: Ta ni ọ́? Kí ni ọ́? Kí lo jamọ́? Kí lo jẹ́? Kílo jásí? Kí lo ń wá? Kí lo ń fẹ́? Kí lo ń wò? Kí lo ń rí? kí lo ń rò? Kí ní ṣe ọ́? Níbo lo ti ń bọ̀? Níbo lò ń rè? Níbo lo ń gbé? Níbo lo ń gbé? Níbo lo ń rìn? – dá mi lóhùn! Ọmọ ènìyàn dá mi lóhùn ni gbólohùn kan. Dájúdájú ìwọ dáràn lónìí, ìwo gun igi kọja ewé, ìwọ já láti òkè bọ́ sínu kànga, ìwọ jẹ májèlé àìròtẹ́lẹ̀, ìwọ rí oko tí ó kún ìwọ gbin ẹ̀pà sí i. Ìwọ aláìgbédè ọkùnrin, ìwọ kò mọ̀ pe kìnnìún àti agbọnrin kì í fi ojú ri ara wọn, àti pé ẹkùn òun mààlúù kì í ṣe ọ̀rẹ́ pọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ti ológbò bá fi ojú kan èkúté ni ayé èkúté yóó pin! – ìwọ rí mi, èmi rí ọ, èmi ń bọ̀, ìwọ náà ń bọ̀, ìwọ kò bá ẹsẹ̀ rẹ sọ̀rọ̀, ìwọ ń rìn bí aláìbíkítà níwájú mi. ẹ̀rù kò bà ọ́ ni ndan? Wọn kò ròhìn mi fún ọ rí ni ndan? Agbárí àwọn tí ó jù ọ́ lọ ń bẹ nínú ìṣaasùn mi, eegungun ẹ̀hìn wọn ń bẹ ni kọ̀rọ̀ oyàrá, gẹ̀ǹgẹ̀ àyà àwọn ọmọ aláìgbọràn ni èmi sì fi ń jókòó nínú ilé mi. Èmi ni ẹbọra kékeré inú ọ̀gán, orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Èṣù-kékeré-òde. Ìjà ni ó dé pẹ̀lú èmi àti ẹnìkan ni òde-ọ̀run ni wọ́n wí pé mo ṣe àbòsí s’’i Ọlọ́run Ọba, èyìínì ni àwọn ẹ̀dá abàmì wọ̀n-ọnnì bá fi pinnu wí pé àfi dandan bí mo bá kúrò ni òde ọ̀run. Mo kúrò ni òde ọ̀run mo bá ìsàlẹ̀ ilẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni mo gbé ọgọ́rùn-ún ọdún láàárin àwọn òkú tí ń bẹ ni ìssàlẹ̀ ilẹ̀ mo si kọ́ onírúurú ọgbọ́n lọdọ wọn, àti ìgbà náà ni mo sì ti mọ̀ pé, nínú ikú ti gbogbo àwọn ọmọ aráyé ń kú, ìba díẹ̀ni ó jẹ́ àtọ̀run wwá nínú wọn – àwọn aráyé a máa fi ọwọ́ ara wọn ṣe ara wọn; òmùgọ̀ a máa pa ẹlòmíràn láìròtẹ́lẹ̀, àṣejù iṣẹ́ a máa pa ẹlòmíràn láìròtẹ́lẹ̀, ọ̀lẹ-ṣíṣe a máa pa ẹlòmíràn láìròtẹ́lẹ̀, wọ̀bìà a máa pa ẹlòmíràn láìròtẹ́lẹ̀, ojúkòkòrò a má pa ẹlòmíràn láìròtẹ́lẹ̀. Ìgbà mìíràn alágàbàgebè a máa wá ọ̀nà àti pa ẹlòmíràn ṣùgbọ́n dípò onítọhùn òun pàápàá á lọ si àjùlé ọ̀run; ìgbà mìíràn abínúkú ọ̀rẹ́ a máa wá ọ̀nà àti pa ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n dípò onítọ̀hún òun pàápàá á lọ sí àjùlé ọ̀run, ìgbà míràn olówó a máa wá ọ̀nà àti pa tálákà ṣùgbọ́n dípò onítọ̀hún òun pàápàá a lọ si àjùlé ọ̀run; ìgbà mìíràn ẹni kékeré a máa wá ọ̀nà àti pa ẹni ńlá ṣùgbọ́n dípò onítọ̀hún òun pàápàá a lọ si àjùlé ọ̀run. Oníṣkúṣ ń fi ikú ṣiré, onínàákúnáà ń fi ikú ṣiré, onírìnkurìn ń fi ikú ṣire, onígbèéraga ń fi ikú ṣiré, onírìkíṣí ń fi ikú ṣiré. Nítorí ni ni ńkọ́? – Nítorí Ẹlẹ́dàá ń wo ẹ̀dá pẹ̀lú iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀dá, àti ìrìnkèrindò ẹ̀dá láàárin àwọn ẹ̀dá, bẹ́ẹ̀ ni Ẹlẹ́dàá kò ní ṣàìfi èrè iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀dá fún ẹ̀dá bíó ti wù tí àyípadà dé tó, yálà ní òde ayé tàbí ni òde ọ̀run. Èmi ni ẹbora kékeré inú ọ̀gán, orúkọ ẹni tí ń jẹ Èṣù-kékeré-òde. Ìgbà ti mo ni ibbùgbé àwọn òkú tán ni mo wá sí aginjù Ìdákẹ́rọ́rọ́ ti mo fi òkìtì ọ̀gán ṣe ilé mi. Ní aginjù yìí ni mo bá àwọn ẹranko, ibẹ̀ ni mo bá àwọn ẹyẹ, ibẹ̀ ni mo sì bá àwọn àǹjànnú ṣùgbọ́n gbogbo wọn ni mo lé lọ féfé tobẹ́ẹ̀ tí n kò ri ẹni kan bá gbé pọ̀ mọ́ tí mo wà ni èmi nìkan ṣoṣo tí mo ń jẹ́ ewéko inú igbó kiri. ṣùgbọ́n lónìí yìí tí mo déédéé ri ọ láìròtẹ́lẹ̀, mo dúpẹ́, orí mi gbé ǹkan pàdé mi, nítorí ọjọ pẹ́ díẹ̀ tí mo ti ri ẹran ènìyàn jẹ mọ. Bí mo bá pa ọ́ tán n ó gbádùn ẹran rẹ fún ọjọ́ mẹ́ta. N ó fi agbárí rẹ se ọbẹ̀ ẹ̀fọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìbàdí rẹ yóò máa ṣe ọ̀rá ṣìnkìn nínú ọbẹ̀ ata. N o sì kóèyí tí ó ba kù lára rẹ pamọ́ sínú ilé mi, nínú òkìtì ọ̀gán – Háá! Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè lónìí, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ irúnmalẹ̀ gbogbo lónìí, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn àǹjànnú ayé, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ oògùn àwúre inú àpò mi, bẹ́ẹ̀ ni mo dúpẹ̀ lọ́wọ́ iwin pàtàkì ńlá nì, Aládé-igbó, ẹbọra tí í ṣe alákòoso òkìtì ọ̀gán, tí ó jẹ́ ìbátan mi.’ Báyìí ni iwin náà sọ si bàbá mi, bàbá mi náà fèsì bí ó ti yẹ ki alágbára fèsì fún alágbára. Ó wo Èṣù-kekeré-òde bí ìgbà bí ìgbà ti jàndùkú obìnrin bá ffi ojú ìbàjẹ́ wo ọkọ rẹ̀, ó wí pé: Ẹni tí ó fi asẹ́ gbe òjò o tan ara rẹ̀ jẹ; ẹni tí ó dúró dé rélùwéè yóó bá ara rẹ̀ ni ọ̀run alákeji; àgbà tí ó rí ejò tíkò sá ara ikú ló ń yá a; ẹranko tí ó bá ń fi ojú di ọdẹ ẹ̀hìn ààrò ni yóò sùn, ẹni tí ó gbójú lé ogún fi ara rẹ̀ fún òṣì ta; ẹbọra ti ó bá fi ojú di mí yóó máa ti ọ̀run dé ọ̀run ni, èmi ọkùnrin ni mo wí bẹ́ẹ̀, òní ni n ó sọ fún ẹ̀yin ẹbọra Igbó-Olódùmarè pé, nígbà tí Ẹlẹ́dàá dá ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé tán, ó fi ènìyàn ṣe olórí gbogbo wọn. Mo fẹ́ kí ìwọ mọ̀ lónìí pé, ìgbéraga ni ìbẹ̀rẹ̀ ìparun, òun ni ìbẹ̀rẹ̀ ìṣubú, ó lòdì sí òfin ènìyàn, ó sì yàtọ̀ si ìlànà Ọlọ́run Ọba, dípò kí ìwọ fi èmi ṣe ìjẹ, èmi lè fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹranko inú igbó, kì ìwọ sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ tí ń fò lórí igi. Lóòótọ́ ìwọ ti ń bá ènìyàn pàdé ìwwọ sì ń sọ wọ́n di èrò inú ìṣaasùn ọbẹ̀. Ṣùgbọ́n, Èṣù-kékeré-òde, má ṣe gbàgbé pé adíẹ̀ ju adíẹ̀, ẹwúrẹ́ ju ewurẹ́; àgùntàn ju àgùntàn; ẹyẹ ju eyẹ; ènìyàn ju ènìyàn; ọdẹ ju ọdẹ - èmi ni mo wí fún ọ, èmi jù wọ́n lọ, èmi kì í ṣe ẹgbẹ́ wọn, ẹgbẹ́ bàbá wọn ni èmi ń ṣe, onígbéraga ni ọ́, ìwọ ẹbọra kékeré inú ọ̀gán, ìwọ Èṣù-kékeré-òde, n kì í ṣe ẹgbẹ́ ìyá ńlá rẹ, ṣíọ̀ rẹ, kí lo jámọ́, síọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀meje, nǹkan dé lónìí, múra jẹ́ ki á kọlu ara wa.’ Ìwọ ọ̀rẹ́ mi, bàbá mi fẹ́rẹ̀ ma ì tí ì pa’ri ọ̀rọ̀ yìí tan nígbà tí àwọn méjéèjì ti kọlu ara wọn, ìjà náà si pọ̀ gidigidi, ènìyàn pàdé àǹjànnú, gbogbo igbó ń pariwo, bí Èṣù-kékeré ti le bẹ́ẹ̀ náà ni Olówó-ayé le, bàbá mi, ọkùnirn náà, ẹni ti ń bẹ ni inú ayé tí ń ja ìjàkadì pẹ̀lú èrò ọ̀run alákeji. Nígbà tí ìjà yìí kọ́ bẹ̀rẹ̀, Èṣù-kékeré gbìyànjú láti ri àyè sọ mọ́ bàbá mi ni ìbàdí, kí ó fi ẹ̀hìn rẹ̀ ti igi ẹlẹ́gùn-ún, kí gbé ẹsẹ̀ onítọ̀hún dé èjìká. Kí ó rún bàbá mi mọ́ inú ìpàǹtí, kí ó bẹ̀rẹ̀ si fi ìyà jẹ ẹni-ẹléni, ṣùgbọ́n eléyìínì ṣòro gidigidi: nítorí bí òun ti ń pa èrò wọ̀nyí, bẹ́l náà ni bàbá mi tún ń ronnú èrò tọ̀hún, tí ó ń wwá ọ̀nà àti mu Èṣù-kékeré ni ibi èjìká kí ó gbé ẹbọra kúkúrú kúrò ní ilẹ̀ tán, kí ó gbe olórí burúkú rékọja àtàrí, kí ó sọ alákọrí sí ọ̀nà jínjín réré, kí Èṣù-kékeré ti ọ̀run dé ọ̀run. Ṣùgbọ́n ǹkan wọ̀nyí kò ṣe é ṣe, nítorí bi òun ti ń múra bí kìnnìún bẹ́l náà ni Èṣù-kékeré ń mura bí àjànàkú tí èruku ńlá ń sọ lójú ọ̀run. Ilẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í mì tìtì, gìrìgìrì ẹsẹ̀ àwọn méjèéjì ju ti ènìyàn mẹ́eàá lọ wọ́n fẹ ojú toto, wọ́n di mọ́ ara wọn bí ìgbà ti ìtàkùn bá dìi mọ́ igi oko, àwọn méjèéjì sì ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ajá ọdẹ, Ọjọ́ ńlá ni ojọ́ náà fún ẹbọra kékeré inú ọ̀gán, orúkọ ẹni ti ń jẹ́ Èṣù-kèkerè-òde. Nígbà tí ó ṣe, iwin burúkú yìí fò mọ́ bàbá mi lágbedeméjì, ibi tí bàbá mi sì ti ń gbìyànjú àti dì i ní ẹsẹ̀ mú ó tún fò si i ni èjìká, nígbà tí ó si di bàbá mi ni ọrùn mú ó gbá a létí tagbáratagbára. Inú bí bàbá mi nítorí ọ̀ràn yí ó si bẹ̀rẹ̀ sí ti ẹwbọra náà lọ títí ó fi dé ìdí igi ẹlẹ́gùn-ún tí o fi agbára ti Èṣù-kékeré mọ́ igi ẹlẹ́gùn-ún èyí tí ó mú kí ẹbọra burúkú yìí kígbé ńlá tí ó sì mú kí ó bẹ́ sílẹ̀ láti èjìká bàbá mi. Lẹ́hìn eléyìínì ni ọwọ́ bàbá mi bá á ni ọrùn ẹsẹ̀ méjéèjì tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi gbé Èṣù-kékeré kọjá àtàrí, nígbà tí ó si jù síwájú pẹ̀lú ìbínú, nírètí àtifọ́ olóríburúkú yìí ni agbárí, ọ̀rọ̀ náà kò bọ́ sí i. Bí bàbá mi tún ti wo iwájú báyìí, ṣánṣán ni ẹ̀dá yìí dúró tí ó ń rẹ́rìn-ín tí ó sì ń wo bàbá mi bí ẹni pé ìjà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni. Lẹ́hìn eléyìí ọ̀ràn náà sú bàbá mi óo sì ki ọwọ́ bọ àpò rẹ̀ ó ń wá oògùn kiri, ṣùgbọ́n ibi tí ó ti ń ṣe eléyìí ni ó ti rrí fèèrè àtìrandíran tí ń bẹ ní ilé wa, bẹ́l ni ó mú fèèrè náà sì gba gbogbo àgbègbè kankan. Ó wí bí ó ti jẹ́ pé Olódùmarè ní ń ṣe alákòóso ìṣẹ́gun, tí ó si jẹ́ pé òun ni ó ni ohun gbogbo ti ń bẹ́ ń inú ayé àti èyí tí ń bẹ ní òde ọ̀run, dúkìá àwọn ọmọ ènìyàn àti ohun àlúmọ́nì ìsàlẹ̀ ilẹ̀, èyí tí ó ń bẹ níi ojú omi àti èyí tí ó ń e ni òfuurufú, ó sì tún wípẹ̀lú bí ó ti jẹ́ pé kò si ìdíwọ́ fún Ọlọ́run Ọba : ohunkohun tí Ẹlẹ́dàá bá fẹ́ ní ń ṣe àti wí pé ẹnikẹ́ni kò le dí Ọlọ́run Ọba lọ́wọ́ àti gbé ẹnikẹ́ni ga; bẹ́l nni elékèé kò le dí Ọlọ́run Ọba lọ́wọ́ àti gbé ènìyàn ga. Bàbá mi wí pẹ̀lú féèrè rẹ̀ pé elékèé dìde ní owúrọ̀ ó dúdú bí ọ̀gẹ̀dẹ̀ etí odò, nígbà tí ó di ọ̀sán, elékèé gbẹ bí igi, nígbà tí ó si di àṣáálẹ́ ó ti jóná pátápátá. Onírìkíṣí wí fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wí pé òun da aṣọ bora, ṣùgbọ́n nígbà tí olóòótọ́ dé ó tọ́ka si ọkùnrin náà wí pé ìhòohò ni ó wà gidigbi. Bẹ́l ni àwọn orin náà ti bàbá mi ń kọ tàánútàánú ni ọjọ́ tí òun àti ẹbọra kékeré inú ọ̀gán fi ojú rí ara wọn. Gbohùngbohùn gba orín náà nínú igbó kankan, bẹ́ẹ̀ ni fèèrè náà dún ju fèèrè ọba lọ, níwọ̀n ìgbà tí orin náà sì ti jẹ orin arò ńkọ́, kò le ṣàì kó wọ ẹbọra náà ni ibi kọ́lọ́fín agbárí lọ; Olóòótọ́ tẹ orí alábòsí ba. Èṣù-kékeré doríkodò bí ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀, ẹbọra inu ọ̀gán ń wo ilẹ̀ tirònútìrònú, ẹ̀dá kékeré la ẹnu rẹ̀ ó si wí pé: Àwọn ọmọ ènìyàn ti yípadà, ọlọ́gbọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dé inú wọn, ojọ́ pẹ́ tí mo ti fi ìhín ṣe ibùgbé, ẹni kan kò gbìyànjú àti yí mi lọ́kàn padà rí, ṣùgbọ́n mo ti kíyèsí i láti ọjọ́ ti Ọlọ́run ti ṣe ẹ̀dá mi pé, onísùúrù kò le kábàámọ̀ láé àfi ẹni tí ó fi òmùgọ̀ ba sùúrù jẹ́: láti oní lọ, n kò ní hùwà ìbàjẹ́ si ọmọ aráyé mọ́, n kò ní kanra si àwọn ọmọ ènìyàn, n kò ní fajúro si àwọn ẹranko, n kò sì ní hùwà ibajẹ́ ọ sí àwọn ewéko inú igbó, nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ti yí mi lọ́kàn padà, n kò ní hùwà ará oko mọ́. Ṣùgbọ́n má ṣe ni èrò láé pé, ìwà ọ̀lẹ ni ó mú mi sọ irú ọ̀rọ̀ wọnyí, nítorí bí ìwọ bá ni èrò wọ̀n-ọnní, a jẹ́ pé èdè mi kò yé ọ: iwọ a sì da bi ẹni tí ó pe àgùntàn ní mààlúù, tí ó pe mọ́tọ̀ ní kẹ̀kẹ́, tí ó pé ayé ni ọ̀run alákeji. Onísùúrù rí ìjà ó ta kété òmùgọ̀ ṣe bí ọ̀lẹ ni, ṣùgbọ́n nígbà tí onísùurù bẹ̀rẹ̀ ìjà, gbogbo àwọn òmùgọ̀ ń wó lulẹ̀ bí igi. Mo dúpẹ̀ lọ́wọ́ rẹ fún orín arò tí o kọ, orin ọlọ́gbọ́ntí ó rán mi létí ẹni tí ó dá mi, bi kò bá sí orin ti iwọ kọ yìí ńkọ́, èmi ìbá jà fún odidi ọjọ́ mẹ́ta - nítorí mo ti ja ìjà bẹ́ẹ̀ rí, mo jà ìjà oṣù mẹ́fà, mo ja ìjà oṣù mẹ́ta, mo sì ja ìjà ọdùn kan gbáko – èmi náà, ẹbọra kékeré inú ọ̀gán, orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Èṣù-kékeré-òde.’ Báyìí ni ẹbọra náà sọ bàbá mi kò sì bínú mọ́ òun àti Èṣù-kékeré ki ara wọn, wọn bọ ara wọn lọ́wọ́, olúkúlùkù sì kọjú si ibi tí ó ń lọ, ṣùgbọ́n gẹgẹ bi ìṣẹ̀dálẹ̀ wa, ìjà kì í lọ lásán kí oníjà ma ni ìfarapa rẹ̀ ya, ó sọ oògùn kan pàtàkì nù, ìkòkò tábà rẹ̀ sì dá. Bẹ́ẹ̀ ni Èṣù-kékeré fi ara pa, tí eyín rẹ̀ méjì ká, tí òrùka rẹ̀ kan sọnù, tí ó si fi ẹsẹ̀ dá, tí ó ń rìn bí onísòbìyà kiri. Ifi rẹ̀ si ni ìwọ̀nyí, tí àwọn ọlọ́gbọ́n fi sọ ìjà di májèlé tí wọ́n ń sá fún un lójoojúmọ́, nítorí ìjà kò yẹ ọmọ ènìyàn, òun da bi egungun ẹja pẹ̀lú ọ̀nà ọ̀fun. Ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ènìyàn, a máa tanná ògùṣọ̀ òyìnbó, wọn a máa wá ìjà kààkiri òde. Olówó-ayé kọjú si ọna rẹ̀, ó ń lọ, òun àti Ọlọ́run Ọba, nígbà tí ó si kù díẹ̀ kí ó la aginjù Ìdákẹ́rọ́rọ́ já ó de ibi odò kékeré kan ti ó ń ṣàn, tí ó ń dán, tí ó si tutù nini, ibẹ̀ ni bàbá mi sì dúró tí ó bu omi si ara, lẹ́hìn èyìínì ó jẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀ pupa, ó mú obì nínú àpò ó da a sí ẹnu, ọkàn re sì balẹ̀ bí ọkàn ẹni tí ó jẹ pọ́n-ùn méjì ní gbèsè, tí Olódùmarè bò ní àṣírí, tí àǹfààní pọ́nun mẹ́wàá wọlé wá bá a. Kò ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá tí bàbá mi kúrò ní ibi odò náà nígbà tí ó fi aginjù Ìdákẹ́rọ́rọ́ sílẹ̀ tí ó si ja sí ibi kan tí ó tobi tí ó sì tẹ́jú pẹrẹsẹ. Ewéko ibẹ̀ tutù yọ̀yọ̀, o dára bí iwájú ile òyìnbó, ibi kékeré sì pọ̀ ju igi ńlá lọ bẹ́l ni àwọn igi kọ̀ọ̀kan ti ń bẹ láàárin àwon ayika náà lẹ́wà púpọ̀, wọ́n dúró wọn rí gbọnrangandan, ara òmíràn funfun, ara òmíràn dúdú, ara òmíràn sì dàbí òṣù,àrè àwọsánmọ̀ tí ó ni dúdú tí ó tun ní pupa. Oju ọ̀nà titobi kan lọ tààrà sí iwájú, èyìínì ni pé ojú ọ̀nà tí bàbá mi ń tọ̀ bọ̀ túbọ̀ sí i. Òkúta ńlá ńlá ni wọn tò si ẹ̀bá ọ̀nà náà apá ọ̀tun àti apá òsì. Lẹ́hìn àwọn òkúta yìí wọ́n gbin igi kékeré bá ojú ọ̀nà lọ, wọ́n tanná wọ́n sì lẹ́wà gidigidi. Ìwọ ọ̀rẹ́ mi, ikú tí ń pa ojúgbà ẹni ń pòwe, nígbà tí Olówó-ayé rí ìwọ̀nyí òun náà mọ̀ pé Igbó Olódùmarè sún mọ́ etílé, bàbá mi múra ó tún ṣòkòtò ṣe. Ọlọ́gbọ́n àti òmùgọ̀ dà bí ọkan náà lákòókò igbádùn ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n yọ gedegbe lákòókò ìyọnu. Bàbá mi hùwwà ọlọ́gbọ́n ní àkókò yí, órọra kó àwọn ǹkan ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀ ó lọ sí abẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ibi wọ̀n-ọnnìó dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú Ọlọ́run ó si wí pé: Ìwọ Ọlọ́run Ọba tó ó dá m,i ìwọ Olódùmarè tí o dá Igbó Olódùmarè, Ìwọ Ẹni ìyanu tí o dá ǹkan iyanu gbogbo, Ìwọ Ẹlẹ́dàátí ó dá gboggbo àwọn ọdẹ tí ń bẹ nínú ayé; àkókò náà dé wàyí tí mo fẹ kí o ṣe alátìlẹ́hìn mi. Àwọn ẹlòmíràn wá si inú ayé ṣùgbọ́n nígbà ti wọ́n fi ayé sílẹ̀ orúkọ wọ́n lọ pẹ̀lú wọn, àwọn wọ̀n-ọnnìrìn kọja nínú ayé bí ìgbà tí ejò kọjá ní orí àapáta a kò si ri ẹsẹ̀ wọn mọ́, ṣùgbọ́n àwọn ẹnlòmíràn wá sí inu ayé nígbà ti wọ́n fi ayé síl�� orúkọ búburú wọn dúró lẹ́hìn wọn, àwọn wọ̀n-ọnnì da bi ìgbà tí àbàwọ́n dudú ba bọ́ si ara aṣọ funfun tí alágbàfọ̀ fọ aṣọ títí tí aṣọ fẹ́rẹ̀ẹ́ fàya tí àbàwọ́n tubọ̀ń hàn kedere. Jọ́wọ̀ Ẹlẹ́dàá mi, má ṣe ṣe mi bi gbogbo àwọn wọ̀nyí. Mó ń tọrọ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ lónìí, pé kí ó ṣe dídǹ inú Rẹ, ki emi le da bi àwọn wọ̀n-ọnnì ti wọ́n wá si inu ayé tí wwọ́n si da bi oṣupa ti ń ṣoore fún àtọmọdọ́mọ. Orúkọ wọn dúró lẹ́hìn àwọn èrò ẹhìn si ń ìje nítorí wọn pé kí àwọn kí ó le dabi wọn. Bí mo ti ń lọ lónìi’, jọ́wọ̀ jẹ kí n padà gẹgẹ bi ọkùnrrin, tó bẹ́ẹ̀ tí, bí ọjọ́ mi bá tilẹ̀ pé ti mo kú, àwọn ènìyàn kò ní le bi ara wọn léèrè lẹ́hìn mi pé ‘Tàbí a bí ọkùnrin náà rí ńdan?’ Olówó-ayé kò wí ju báyìí lọ, Olódùmarè sì gbọ láti ọ̀run alákeji, nítorí kò sí ènìyàn ksn tí ó da bi màlákà, bẹ́ẹ̀ ni kò si aláfẹ̀hìntì kan tí o da bi Ọlọ́run Ọba. Bàbá mi mura, ó ń lọ, ó ń kọrin, ó ń súfèé, ó si ń rìn bí jagunjagun. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́hìn eléiì’tí ó wo iwájú tí ó si rí àwọn obìnrin mejì ti wọn ń bá ojú ọna bọ̀ ti wọ́n si ń sọ̀rọ̀ti wọ́n ń rẹ́rìn-ín ti wọ́n ń pa atẹ́ẹ́ pó pó gẹ́gẹ́ bí àṣà ogunlọ́gọ̀ obìnrin. Àwọn obìnrin méjì yí da bi ẹni pe wọ́n tilẹ̀ fi ibẹ̀ ṣe ilé ni, ti wọ́n ń gbádùn nínú igbó ti wọ́n sí ń ṣe fáàrí bí ẹni pé wọ́n wà ni ààrin ìlú. Ọ̀kan nínú wọn pupa, ó tóbi, ó síngbọnlẹ̀, ó sí da bi ẹni tí ó ti wọ ilé ọkọ, ṣùgbọ́n èyí ekejì kò sanra púpọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ga, ènìyàn dúdú ni, eyín rẹ̀ sì funfun bi àgbàdo àṣẹ̀ṣẹ̀yọ. Arẹwà ni àwọn méjéèjì. Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn bá ti gbajúmọ̀ mu, bẹ́ẹ̀ ni ìrìn ẹsẹ̀ wọn dàbí ìrìn ẹsẹ̀ ènìyàn ti afẹ́ ayé ti sọ di réderède. Nígbà ti wọn pàdé bàbá mi, ó kí wọn àwọn náà si dá a lóhùn bí ó ti yẹ kí ẹni tí a kò mọ̀ rí dá ni lóhùn mọ. Lẹhìn eléyìínì bàbá mi kọjú sí ọ̀nà tirẹ̀ àwọn náà sí kọkú si ọ̀snà tiwọn. Ṣùgbọ́n bí gbajúmọ̀ mejì tọ̀tọ̀ ti ṣe de inu aginjù yí kò le ṣàì ya ẹnikẹ́ni lẹ́nu. Èyí náà ló si mú kí bàbá mi bojúwo ẹ̀hìn láti wò wọ́n, ṣùgbọ́n àkókò náà gan-anni èyí tí ó kéré jù nínú àwọn obìnrin náà bojúwo ẹ̀hìn pẹ̀lú, nígbà tí àwọn méjéèjì si wo ara wọn lójú, wọn rẹ́rìn-ín sí ara wọn olúkúlùkù tún kọjú si ọ̀nà rẹ̀, ó ń lọ. Ẹ̀ẹ̀kejì tí bàbá mi sì tún máa bojúwo ẹ̀hìn náà ńkọ́, ṣe ni ojú òuun àti obìnrin yìí tún ṣe dọ́gbadọ́gba – bẹ́ẹ̀ ni bàbá mi koì tí ì ní obìnrin, àpọ́nni, síbẹ̀síbẹ̀ náà, ó tún rọ́jú, ó ń lọ. ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ẹ̀ẹ̀kẹta wàyì tí bàbá mi sì tún máa bojúwo ẹ̀hìn náà ńkọ́, ṣe ni ojú òun àti obìnrin yìí tún ṣe dọ́gbadọ́gba – bẹ́ẹ̀ ni bàbá mi ko ì tí ì nì obìnrin, àpọ́n ni, síbẹ̀síbẹ̀ náà, ó tún rọ́jú, ó ń lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ódi ẹ̀ẹ̀kẹta wàyí tí bàbá mi tún wo ẹ̀hìn obìnrinyìí tún wò ó ti òun rẹ́rìn-ín ti obìnrin náà rẹ́rìn-ín, tí eyín arẹwà yí sì funfun bí ẹ̀gbẹ́ ògiri tí ènìyàn kùnní ẹfun, Olówó-ayé yí ojú padà, ọkùnrin kọ ìpàkọ́ si ọ̀nà igbó Olódùmarè, bàbá mi tọ obìnrin lọ - kí Olódùmarè gba àwọn ọmọ aráyé lọ́wọ́ obìnrin ìjàngbọ̀n, ti wọ́n ń wé gèlè wọn sí ibi iwájú gẹngẹ. Nígbà tí bàbá mi ń rìn tọ obìnrin yìí lọ obìnrin náà dúró, ṣùgbọ́n ẹnìkejì rẹ̀ rìn síwájú díẹ̀ eléyìínì dúró, ó takáté sí i, nítorí nígbàtí ọkùnrin àti oobìnrin bá ń fẹ́ẹ́ sọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ ẹnì kẹta kò ní ṣàì jẹ́ ìdíwọ́ fún wọn. Wò mí, ọ̀rẹ́ mi, ṣọ́ra ni ìgbésí-ayé rẹ, bí ìwọ bá sin ẹnìkejì rẹ lọ sí ilé ìyàwó àfẹ́sọ́nà rẹ̀, ronú ki o tó dá sí ọ̀rọ̀ ti wọ́n bá ń ṣo nítorí bí ìwọ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yòó da bi àbàwọ́n pẹ̀lú aṣọ funfun, bí wọ́n bá si ń fi ojú rẹ́rìn-ín si ọ wọn kò ní ṣàì máa wí ní ibi kọ́lọ́fín ọkàn wọn pé, ‘Alákọrí yìí kò jẹ́ kí a gbádùn eré wa.’ Nígbà tí bàbá mi dé ọ̀dọ̀ obìnrin náà ó kí ii, àláàfáì kọ́ ni ilée wà bi, ara kò le bí, ṣe kò sí ǹkan? Onítọhun náà si dáhùn dáadáa. N’gbẹ̀hìn idahun rẹ̀, obìnrin yìí béèrè tẹ̀ríntẹ̀rín ó wí pe: Ó da bi ẹni pe mo mọ̀ yín níbìkan rí. Bàbá mi náà si fèsì ó ní, Ó jọ bẹ́ẹ̀ lójú èmi náàm tàbí ilé yín ni ile tí ó wà ní ẹ̀hìnkùlé wa? Bẹ́ẹ̀ ni tòótọ́ ni ile alágbẹ̀dẹ kan wà ni ẹ̀hìnkùlé wa, ọmọbìnrin àjẹ́ kan sì ti ń gbe ilé náà tẹ́lẹ̀ kí ó tóó di pe Olówó-ayé bẹ̀rẹ̀ si máa káàkiri igbó ọdẹ, ó sì ti pẹ́ ti bàbá mi ti rí ọmọbìnrin náà mọ. Àṣé ọmọbìnrin yìí ti kúrò ní ilé, òun àti ẹgbọn rẹ̀, wọ́n si ti fi igbó Olódùmarè ṣe ibùgbé wọn, ìgbà tí bàbá mi sì ṣe ìbéèrè yí ni ọran náà tó yé e. Obìnrin náà dáhùn ó si wi pé: Lóòótọ́ èmi ni ọmọbìnrin náà ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ àjẹ́dìran, ẹni ti ń gbe ilé alágbẹ̀dẹ. Ìjà ni ó de ní ijọ́sí ni àwọn ara ilé wa purọ́ mọ wa, ti wọ́n wi pe awa ni a pa àwọn lọ́mọ jẹ, bẹ́ẹ̀ ni àkókò tí mo ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí, emi àti ẹgbọn mi kò ì tí í ní àjẹ́, orúkọ tí kò yẹ wa ni ọmọ aráyé fi fún wa, nígbà tí oṣì mẹta si fi máa pé gbogbo ènìyàn jákèjádò ìlù wa ni wọ́n ti gbàgbọ́ pe àjẹ́ ni èmi àri ẹgbọn mi. Bẹ́ẹ̀ ni òmùgọ̀ àwon ènìyàn pọ̀ tó? Bí ẹni mejì tàbí mẹta bá ti ń sọ ǹkan kan àwọn ìyókù kò ní ronú ní tiwọn mọ́, àwọn náà a si máa sọ ohun tí ojú wọn kò tó. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn enìyàn fún èmi àti ẹgbọn mi ní orúkọ tí kò yẹ fún wa. Àsẹ̀hìnwá-àsẹ̀hìnbọ̀ ọ̀rọ̀ náà, inú bí wa, a wá àjẹ́ lọ a sì rí i, a sì fi ìbínú sọ ara wa di àjẹ́ láti ọjọ́ náà títí ó fi di òní olónìí. Báyìí ni àwọn ẹlòmíràn wà nínú ayé ti wọ́n da bi gbòǹgbò ojú ọ̀nà ti wọ́n jẹ́ ohun ìdíwọ́ fún àwọn ọmọ Olódùmarè. Ẹni ti kò hùwà èké wọn a wi pe olúwaarẹ̀ ń hùwà èké títí onítọhun á fi pinnu lọ́kàn rẹ̀ pé, níwọ̀n ìgbà tí ọmọ aráyé ti wí pé òun ṣe ǹkan tí òun kò ṣe, ó yẹ kí òuun kúkú ṣe bẹ́ẹ̀ dandan – eléyìí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìṣubú fún àwọn ọmọ tí Olódùmarè dá sí orí ilẹ̀ ayé. Ìwọ ọkùnrin alágbára, nígbà ti èmi àti ẹ̀gbọ́n mi di àjẹ́ tán a fi ojú ènìyàn rí ǹkan, nítorí a pa kékeré jẹ, a pa àgbàlagbà jẹ, a sipa ènìyàn pàtàkì ni àwùjọ. Nígbẹ̀hìn, ọ̀ràn yìí bí Ọlọ́run Ọba nínú, nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ aráyé hùwà òmùgọ̀ ṣaájú rí, àwa náà tún ti hùwà ìlábùrù baba ọ̀bọ. Nígbà tí ó sì di òwúrọ̀ ọjọ́ kan báyìí, ògbólógbòó àjẹ́ kan dí wa mọ́ ilé, bẹ́ẹ̀ ni eléyìíní gbóna ju àwa lọ, ẹ̀dá burúkú náà bá wa fi ìjà pa ẹẹ́ta, ó lé wa kúrò nínú ilé a si sáré dé Igbó Olódùmarè koko. N kò gbàgbé ọ̀ràn yìí títí ọjọ́ ayé mi nítorí bíkò bá si eléyìí náà ńkọ́, èmi ìbá ti rí ọkùnrin tí ó máa fẹ́ mi. Nítorí èyí, mo bẹ̀ ọ́ gidigidi, ìwọ arẹwà ọkùnrin, má ṣe rò mi si alábùkù nípa ìbéèrè ti n ó ṣe. Mo fẹ kí o rántí pé àṣà burúkú àwọn ọmọ ènìyàn kò fún obìnrin ni àyè àti yan ọkọ tí ọkàn rẹ̀ fẹ́, àwọn ọkùnrin ni ó ní àyè àti kọ́ wí fún obìnrin wí pé kí ó fẹ́ àwọn. Bi ọkùnrin kan wu obìnrin láti fẹ́ àti sọ ọ́ jade lẹ́nu á di ìṣòro fún obìnrin. Àṣà àwọn ọmọ ènìyàn yí ń fi ìyà jẹ apá kan nínú àwọn ọmọ ènìyàn bẹ́l ni bi ọkùnrin ri ejò bí obìnrin pa ejò, bí ejò kò bá ti lọ kò lòdì ssi òfin. Mo fẹ́ kí ó yé ọ kedere pé bí ọkùnrin bá wu obìnrin bí obìnrin náà bá si fi ifẹ́ yìí han si ọkùnrin eléyìínì kò lòdì si òfin. Aláìmòye ènìyàn wi pe onífẹ̀ẹ́kúfẹ̀ẹ́ni obìnrin tí ó tìkara rẹ̀ fẹ́ ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ni kí obìnrin tóó ṣe irú èyí, iná ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ a máa lágbára ju iná ìléru. Láìṣe àníàní, ìwọ alágbára ọkùnrin, ìwọ kò si láarin àwọn aláìmoye. O wù mí gidigidi, mo fẹ́ kí o jẹ́ baálé mi, mo fẹ́ kí á jọ máa wọlé, kí á jọ máa jáde. Wo mi, ọ̀rẹ́ mi, ìyàlẹ́nu nínú ìtàn yí ni pé, ọ̀rọ̀ dídùn láti ẹnu obìnrin yìí mú kí bàbá mi tọ́ ìfẹ́ wò fún ìgbà kínní ní ìgbésí-ayé rẹ̀. Ìfẹ́ ru bò ó lójú bí ẹmu inú akèǹgbè, Olówó-ayé ti ìtorí ẹwà ó gbàgbé ìwà, ó ti ìtorí ojú dídán ó gbàgbé ọgbọ́n, ó ti ìtorí eyín ffunfun ó sọ ara rẹ̀ di baálé àjẹ́, àti ọjọ́ náà ni bàbá mi sì ti gbé ìjàgbọ̀n lẹ́hìn tí ó ń pe ìjàngbọ̀n lóbìnrin. Ó tó oṣù mẹ́ta lẹ́hìn èyí ki wọ́n tóó gbé ara wọn ní ìyàwó ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ti pinnu àti fẹ ara wọn tí bàbá mi sì tún ti gbé àpò ọdẹ rẹ̀ lé èjìká tí ó fi àdá rẹ̀ si àkọ̀ tí ó kọjú si ọ̀nà igbó Olódùmarè ni obìnrin náà ti tẹ̀lé e, òun àti ẹgbọn rẹ̀ ti wọ́n jọ ń rìn kiri. Ọba igbó Olódùmarè ni ó wáá ṣe ìgbéyàwó fún wọn nígbẹ̀hìn. Ìwọ yóò máa gbọ́ ìtàn eléyìínì níwájú. Nígbà tí àwọn obìnrin mejì yìi’kọ́ tẹ̀lé bàbá mi wọ́n ṣe bí yóó tètè padà ni, wọn kò mọ̀ pé o ń lọ ṣe ọdẹ nínú Igbó Olódùmarè ni. Ṣùgbọ́n nígbà ti wọ́n rìn díẹ̀, obìnrin náà béèrè ó ní, Níbo ni à ń lọ gan-an? Bàbá mi náà fèsì o ní, mo ń lọ ṣe ọdẹ. Obìnrin yìí tún dáhùn pẹ̀lú ó ní, kí ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé? Bàbá mi náà dáhùn ó wí pé, mo gbẹ́kẹ̀lé {ibọn, mo gbẹ́kẹ̀lé àdá, mo gbẹ́kẹ̀lé oògùn, mo si gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Ọba. Lẹ́hìn èyí obìnrin náà tún dáhùn o ní, Ìwọ dé Igbó Olódùmarè rí ńdan? Bàbá mi náà si tún dá a lóhùn ó ní, N kò dé Igbó Olódùmarè ri ṣùgbọ́n mo gbúròó Igbó Olódùmarè rí. ibi ti wọ́n ọ̀rọ̀ náà de ni èyí tí ọ̀gbọ́n obìnrin náà dáhùn tí ó wí pé: Ìwọ ọmọkùnrin, Igbó Olódùmarè léwu gidigidi, ilé ìjàǹbà ni, igbó ìbanujẹ ni, bi ìwọ kò bá ṣọ́ra ìwọ yóò kábàámọ̀ lílọ rẹ, ṣùgbọ́n bu ìwọ bá gbá ìmọ̀ràn ìwọ yóò ni orúkọ rere lẹ́hìn ọ̀la, àwọn ọmọ ènìyàn kì í lọ si ibẹ̀ ki wọ́n padà bọ̀, ṣùgbọ́n bi Ẹlẹ́dàá ti mu kí ìwọ ṣe alábàápàdé wa yìí ńkọ́, ìwọ padà bí ìwọ bá gbọ́ràn si wa lẹ́nu. Kí ìwọ tóó wọ inu igbó náà pàápàá ẹ̀rù oníbodè ibẹ̀ ń bà mi, nítorí iwin burúkú ni, Àǹjànnú-ìbẹ̀rù ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́. A máa gbé ìwé ńlá kan sí ọwọ́ rẹ̀ nínú èyí tí orúkọ ẹ̀ṣẹ̀ tí gbogbo ọmọ aráyé ń ṣẹ̀ wà; wọ́n to orúkọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀n-nnì lẹ́sẹẹsẹ lọ: ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, èkè, ẹ̀gàn, orúkọ-bíbàjẹ́, àìnítìjú, ìlara, ìgbéraga, ojúkòkòrò àti onírúúrú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá mìíràn gbogbo, lẹ́hìn èyí, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míràn tí ó da bi ẹni pé wọ́n kéré ni wọ́n tobi níwájú àǹjànnú-ìbẹ̀rù tí i ṣe oníbodè igbó Olódùmarè. Ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni wí pé kí ọmọdé jẹ ẹ̀kọ mẹta nígbà tí a wí fún un pé kí ó jẹ méjì, kí á rán ọmọdé lọ sí òde kí ó máa ṣiré lójú ọ̀nà, kí ọmọdé lọ sí odò ki ó fọ́ akèǹgbè mọ́lẹ̀, ki ọmọdé wọ aṣọ tuntun lánàá kí aṣọ bàjẹ́ lónìi, kí á ṣe ìbéèrè kékeré kí ọmọdé purọ́ fún ni, kí á mu ọmọ lórí irọ́ kìínní kí ọmọ purọ́ kejì, kí á mu ọmọ lorí irọ́ kejì kí ó purọ́ kẹta, kí ó sì wáá dà bí ẹni pé ọmọdé ń gbé àpótí irọ́ kiri – gbogbo nkan wọnyi nì ó wà nínú ìwé àǹjànnú-ìbẹ̀rù tí í ṣe on;ibodè igbó Olódùmarè. Ki ẹnikẹ́ni tóó wọ inu igbó náà, iwin yìí a wí pé kí olúwarẹ̀ ṣe ìbúra bí òun bá ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ wọnnì rí tàbí òun ko ṣẹ̀ wọ́n rí, bí olúwaarẹ̀ kò bá le búra a fa kùmọ̀ rẹ̀ yọ, a fọ́ ọ ní kùmọ̀ ní àtàrí, a nà án ní igi lẹ́hìn ọrùn, a dá olúwaarẹ̀ ní ìbàdá, onítọ́hùn a di ẹni tí ń rìn yẹ́ńkúyẹ́ńkú kiri. Bí olúwaarẹ̀ bá sì búra èké wéré tí olúwaarẹ̀ bá wọ igbó yìí ni kìnnìíun olójúmẹ́rìndínlógójì ti ń bẹ nínú igbó Olódùmarè yóó pa olúwaarẹ̀ jẹ. Nítorí náà ìwọ Olówó-ayé, múra kí o fún ṣòkòtò le. Bí obìnrin náà tí dakẹ́ ọ̀rọ̀ yí tí bàbá mi si ń fẹ́ẹ́ fún un ní èsì ni ìyàwó rẹ̀ àfẹ́sọ́nà tuntun dáhùn, ó rẹ́rìn-ín músẹ́, ó wo ẹ̀gbọ́n rẹ lójú ó si si pé: Ìwọ ẹ̀gbọ́n mi ọ̀wọ́n, ẹni tí ó ti ń tọjú mi láti ìgbà èwe mi wa, máṣe fi mi silẹ̀ ní èmi nìkan, nítorí àlàáfíà ẹ̀gbọ́n ti àbúrò ni, ibànújẹ́ ẹ̀gbọ́n, tí àbúrò ni; bí iyèkan si ń dide si iyèkan tí ìbátan ń fi igi gún ara wọn lójú, síbẹ̀síbẹ̀ ara ilé ẹni kò ní ṣàì ṣe ará ilé ẹni. Ran olufẹ mi lọ́wọ́ nípa ọ̀ràn yí nítorí apá rẹ̀ nìkan kò ká a; apá tèmi pàápàá kò le ká a: ọgbọ́n ọmọdé kò le dúró lára ọgbọ́n àgbàlagbà. Bí a ti ń lọ si Igbó Olódùmarè yí ẹ̀rù kò le bà mi ju bẹ́ẹ̀ lọ, bí iwọ bá ń ṣe ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n ti inú Ẹlẹ́dàá bá si dùn si ọkọ mi àfẹ́sọ́nà, òun kò ní ṣàìpadà dé ilé dandan. Bayìí ni Àjẹ́dìran sọ tí ó gbé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lé ibi gíga. Ggẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àwọn àgbà tí ó wí pé ẹni tí ó bá ọwọ́ í wẹ̀ á bá àgbàlagbà jẹun, inú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ dùn ó si wí pé: mo dúp púpọ̀ pé ìyá mi bbí ọ pẹ̀lú mi. Àwọn ẹlòmíràn rí ilé ọkọ wọ́n gbàgbé ìdílé wọn, àwọn wọ̀nyí ni àfòmọ́ tí kò ni gbòǹgbò, tí kò lè dá dúró láì jẹ́ pé ó fi ẹ̀hín ti igi bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ tí igi ba wó ni ayé àfòmọ́ pin, ọjọ́ tí àwọn wọ̀n-ọnnì ba ri ìdíwọ́ ní ilé ọkọ àtisọ̀rọ̀ fún àwọn ara ilé wọn yóó di ǹkan: lẹ́hìn èyí wọ́n á pòṣé, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ si ssọkún, omi òmùgọ̀ a máa jade láti ojú wọn, àmódi gọ̀ǹgọ̀ṣú a máa dààmú ihò imú wọn, àtijẹun á di ìṣìro. Ìríra ni lójú Olódùmarè, wí pé kí igi ńlá gbàgbé gbòǹgbò, kí ọmọbìnrin rí ilé ọkọ kí ó gbàgbé ìbẹ̀rẹ̀ òun. Ṣùgbọ́n, iwọ Ajẹdiran, o kò si ni ipò àwọn aláìgbọ́n; ẹ̀gbọ́n rẹ jẹ pàtàkì fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni àbúrò tí ó ba gbé ẹ̀gbọ́n ga lónìí kò ni ṣàì ri ìgbéga ẹhin ọ̀la, nítorí ojú àwọn ọmọ ẹ̀hìn kò fọ́, ó là silẹ kedere. Oniírúurú ènìyàn ní ń bẹ ní inu aayé, onígbèéraga kún inú ayé, ẹni tí kò ní owó ilé ilẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ti dé fìlà àimọ̀kan sí àtàrí. Àjẹ́dìran, ṣe akiyesi ìwà tí Olódùmarè fi jíǹkí rẹ. Ìwà rẹ yóò gbé ọ ga, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ o. Èmi náà kò ní hùwà ìwọ̀sí, kí n dàbí ẹ̀gbọ́n tí ó ń hu ìwà aburo, tí ó sọ iò ara rẹ̀ nù tí ó ń bá rìkíṣí kiri. N ó sa ipá mi fún ọ, n ó sa ipá mi fún ọkọ rẹ, n ó si múra gidi, ó yá, ẹ jẹ́ kí á máa lọ. Ìgbà tí obbìnrin yìí dakẹ́ ọ̀rọ̀ – ísọ ó ki ọwọ bọ àpò yẹ̀rì rẹ̀ óo sì mú èèso igi dídán kan jáde, lẹ́hìn ìgbà tí ó yẹ̀ ẹ́ wò díẹ̀ ó sọ ọ́ sí ẹnu. Eléyìí ni bàbá mi rí mọ - kò sì rí obìnrin náà mọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀ ti eṣinṣin kan bà le oju egbó bàbá mi kékeré kan, ojú ẹsẹ̀ tí ó fi ya igi ní ìgbà ìjà Èṣù-kékeré-òde, ti bàbá mi sì lé eṣinṣin náà kúrò ṣe ni eṣinṣin yí padà tí ó di ejò tí ó bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ mọ́ ọn ní ẹsẹ̀, tí bàbá mi si niláti máa sáré kiri. Ìgbà tí ejò sì tún yí padà ó di èkúté, èkúté tún yi padà ó di òkété, òkété yípadà ó di ìgbín, ìgbín yípadà ó di ìjàpá,ìjàpá yípadà ó di òjòlá, òjòlá yípadà di kìnnìun, kìnnìún yí padà ó di àjànàkú, nígbà tí àjànàkú sì yí padà ó di obìnrin tí i ṣe ẹ̀gbọ́n ìyàwó bàbá mi. Ó kọjú sí bàbá mi ó fi èso igi tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ fún un ó si wí pé: gbá eléyìí, mo ti dán an wò lójú rẹ ó sì ti jẹ́, ìgbàkígbà tí ìjàǹbá bá dé, sọ ọ́ si ẹnu, dárúkọ ǹkan tí iwọ ba fẹ láti dà ìwọ yóó si yí padà si ǹkan náà wéréwéré. Olówó-ayé dúpẹ́ lọ́wọ́ obìnrin yìí, Àjẹ́dìran sì dúpẹ́ nítorí olùfẹ́ rẹ̀ tuntun yìí, lẹ́hìn náà gbogbo wọn múra wọ́n ń kó rẹirẹi lọ. Láìpẹ́ wọ́n yọ si igbó Olódùmarè ṣùgbọ́n ilẹ̀ ń ṣu lọ bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le wọ igbó burúkú náà ní òru àfi ẹni tí gọngọ bá máa sọ mọ́ lára. Nítorí onírúurú àwọn ẹ̀dá abàmì gbogbo ni wọ́n máa ń ṣire kiri ní òru, àti èyí tí ó kéré àti èyí ti ó tóbi, àti èyí tí ó ni ojú àti èyí tí kò ní, olórí-méjì àti olórí-mẹ́ta èyí tí ó wà ní ìhòòhò àti èyí tí ó fi ewé bora, èyí tí ó da bi ìjímèrè àti èyí tí ó ní ìwo lórí bí ẹranko: onírúurú àwọn nǹkan báwọ̀nyí kún igbó náà dé ẹnu, nígbà tí ó bá sì di orù ggbogbo wọn a máa ṣiré wọn a máa sáré kiri. Nítorí ìdí èyí, inú òkúta kan báyìí ni bàbá mi àti àwọn obìnrin wọ̀nnì sùn mọ́jù ọjọ́ náà. Ṣùgbọ́n ki wọ́n tóó sùn ní alẹ́, Àjẹ́dìran wi fún bàbá mi pe òun rántí oògùn kan báyìí tí ó wà ní àpò tòbí òun, òróró kan báyìí ni, ó si mu òróró náà ó fi pa ọkọ rẹ̀ tuntun yìí lára ó wí fún un pe nígbà tí ilẹ̀ bá máa fi mọ́ yóò tubọ̀ lágbára sí i. Òótọ́ náà nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́ egungun bàbá mi le ju ti ìnàkí lọ ojú rẹ̀ si ti yípadà, bàbá mi di olójú-pupa, lílù tí ó si lu ìyàwó tuntun yìí níbi tí ó ti ń bá onítọ́hùn ṣe àwàdà fẹ́rẹ̀ ṣe é ní èṣe. Nígbà tí ó tó àkókò àti máa jẹun òkèlè bàbá mi tóbi ju òroǹbó lọ ó sì ń jẹun ní ìgbà tí mààlúù bá ń jẹ koríko. Bí oúnjẹ ti parí ni ó dìde tíi ó gbé àpò ọdẹ rẹ̀ kọ́ apá o sì gbé àkọ̀ àdá kọ́ èjìká p��̀lúu ìbọn tí o dúdú tí ó sì kún fún ẹ̀jẹ̀ gbogbo. Olówó-ayé fi orí lé ọ̀nà igbó Olódùmarè ojú rẹ̀ sì le koko bí ojú ẹni ebi ń pa. Nígbà ti wọ́n yọ sí igbó Oódùmarè ti wọ́n ń wo oníbodè lọ́kàn-án-kán àwọn obìnrin méjì wọ̀n-ọnnì yí ara padà wọ́n di ẹyẹ nítorí èyìínì kò ṣòro fún wọn: àjẹ́ ni wọ́n. Èyí ẹ̀gbọ́n fò ó bà lé orí igi ràbàtà kan tí ń bẹ ní ẹnu ibodè, èyí àbúrò tí ó sì jẹ́ ìyàwó ń fò le orí àwọn igi kékeré ẹ̀bá ọna lọ ó ń tẹ̀lé bàbá mi bi onítọhùn ti ń ba ojú ọ̀nà lọ. Báyìí ni ó ku bàbá mi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ènìyàn tí àwọn alábàáṣiré rẹ̀ ń lọ gẹ́gẹ́ bíẹyẹ. Síbẹ̀síbẹ̀ bàbá mi kò kọ ikú, kò kọ àrùn, kò bẹ̀rù ìbànnùjẹ́ àìròtẹ́lẹ̀, kó bẹ̀rù wàhálà inú igbó tí ó dúdú mirinmirin. Olówó-ayé ń lọ, òun àti Ọlọ́run Ọba. Ìwọ ọ̀rẹ́ mi, ọ̀rọ̀ pọ̀, kò yẹ kí n tilẹ̀ máa sọ ìyókù ipọ́njú wọ̀n-ọnnì fún ọ níssìyí. Mo rò pe ó yẹ ki n fi ìyókù di ọ̀la. Kò yẹ kí ènìyàn ṣe ju ibi tí Ọlọ́run fún un ní ipá mọ. Iṣẹ́ ti òní tó máa retí mi ní kùtù hàì òwúrọ̀ ọ̀la. Ó dìgbà o, kí ìyàwó rẹ̀ fún mi. ÌJÀ IBODÈ IGBO OLÓDÙMARÈ Báyìí ni ọkùnrin náà sọ tí ó lọ ní ọjọ́ náà, bí ilẹ̀ si ti ń mọ́ ní òwùrọ̀ ọjọ́ kejì ni mo tún rí i. A kò tètè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọjọ́ kejì yìí nítorí àwọn àbúrò mi ọkùnrin, ìbátan mi ní ìdí ìyá mi mú ọ̀rọ̀ kékeré kan báyìí wá sí ọ̀dọ̀ mi mo sì tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ mi náà kí ó jẹ́ kí n dá wọn lóhùn tán. Lẹ́hìn èyí èmi àti ọ̀rẹ́ mi lọ sí ibi tébùrù a sì jẹun. Ìgbà tí a simi díẹ̀ lẹ́hìn óunjẹ, a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wa. Ó ń ba ìtàn náà lọ ó sì wí pé: Ìwọ, ọ̀rẹ́ mi, ó rántí lánàá pé ibi tí a bá ọ̀rọ̀ yìí dé ni ibi tí bàbá mi ti kọ ojú sí Igbó Olódùmarè tí ó ń lọ, òun àti ìyàwó rẹ̀ àfẹ́sọ́nà ti wọ́n bá ara wọn pàdé nínú igbó ti wọ́n si ń lo àyè kékeré ti wọ́n rí tí wọn ń gbàdún ìgbési-ayé wọn láàárin igi àti ọ̀pẹ. Mo sì tún sọ pẹ̀lú pé àna bàbá mi obìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ìyá mi náà wà pẹ̀lú wọn. Nígbà tí bàbá mi yọ sí Àjànnú-ìbẹ̀rù ti í ṣe oníbodè Igbó Olódùmarè òun náà mọ̀ pé òun dé ọ̀dọ̀ ẹbọra pàtàkì kan. Iwin yìí wọ ẹ̀wù péńpé tí ó dà bí ẹ̀wù ọdẹ pẹ̀lú ṣòkòtò kékeré kan tí kò ju orúnkún lọ, gbogbo ìwọ̀nyí kún fún ẹ̀jẹ̀ ó ń pọ́n kankan. Okùn igi ńlá kan ni ó fi ṣe ìgbànú tí ó sán mọ́ ara rẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ̀ kún tí ó dà bí irun orí aṣiwèrè tí oríṣiríṣi ìpàǹtí sì kún ibẹ̀ kítikìti. Láàárin orí rẹ̀ ni ihò kékeré kan ń bẹ èéfin kan sì ń rú látti ààrin ibẹ̀ jáde. Ẹfun àti osùn ni òun fi ṣe ọ̀sọ́ aláràbarà sí gbogbo ara, àti ojú àti imú ẹbọra náà sì dàbí ẹ̀gbẹ́ ògiri ilé òrìṣà, ó ba ni lẹ́rù gidigidi. Kùmọ̀ àti ọ̀gọ, ẹrù pàṣán àti ogunlọ́gọ̀ òkúta, egungun ènìyàn àti agbárí ẹranko, àgógó ẹnu ẹyẹ àti ọ̀ké àìmoye ìkarawun ìgbín ni ó yí Àǹjànnú-ìbẹ̀rù ká, ẹni tí i ṣe oníbodè Igbó Olódùmarè: iwin burúkú ni. Nígbà tí bàbá mi yọ ní ìsàlẹ̀, iwin náà gbé ìwé rẹ̀ nì lọ́wọ́, ó ń kà á, nígbà tí ó sì rí bàbá mi, ó gbé ìwé náà sílẹ̀ ní apá kan, ó yẹ kùmọ́ rẹ̀ wò, ó fi ọwọ́ ba àwọn ẹrù pàṣán, nígbà tí ó sì wo àwọn ohun ìjà wọn-ọnnì tán, ó bú sí ẹ̀rin, ó fi ọwọ́ tẹ ìbàdí, ó rìn díẹ̀ síwájú, ó ń wo Olówó-ayé bí ó ti ń bọ̀ bí aláìbàkítà ènìyàn, tí ó ń rìn bí jagunjagun. Bí ó ti kù díẹ̀ kí bàbá mi dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, bàbá mi ké tagbáratagbára ó sì wí fún iwin náà pé: Njẹ́ ìwọ ni Àǹjànnú-ìbẹ̀rù tí i ṣe oníbodè Igbó Olódùmarè bẹ́ẹ̀? Òun náà sì dáhùn ó ní, Èmi ni, èmi náà ni, èmi ọkùnrin náà nì. Lẹ́hìn èyí bàbá mi wí pé, Njẹ́ bí ó bá ṣe ìwọ ni oníbodè, ṣí ‘lẹ́kùn fún mi, mo ń fẹ́ẹ́ lọ ṣe ọdẹ, ṣe wéré, ojú ń kán mi. Ṣùgbọ́n Àǹjànnú-ìbẹ̀rù bú sí ẹ̀rín ó sì wí pé: Ìwọ kò mọ nǹkan tí ń bẹ, wíwọlé tàbí kí ni? Ẹnikẹ́ni kò lè wọlé láì jẹ́ pé olúwaarẹ̀ bá búra nínú ìwé mi, èmi ni Àǹjànnú-ìbbẹ̀rù tí í ṣe oníbodè Igbó Olódùmarè, èmi kì í ṣe ẹbọra ọjọ́ òní, ọjọ́ pẹ́ tí mo ti dé ìhín, ọdùn mi fi díẹ�� dín ní ẹgbẹ̀wá ni. Bọ́ sí ìhà ìhín, wáá búra fún mi. Bí ìwọ bá búra èké, kìnnìún á pa ọ́ jẹ; bì ìwọ kò bá sì búra, ìyà à jẹ ọ́ gidigidi: ọ̀go lẹ́hìn aṣiwèrè, ìgbà tí mo bá sì nà ọ́ ní igi lẹ́hìn ọrùn, ìwọ á mọ nǹkan tí ń bẹ. Inú bí bàbá mi, Olówó-ayé fọn bí erin, ó ní, Bí ìyà ńlá bá gbé ni ṣánlẹ̀, kéékèèkéé a gun orí ẹni, bí kò bá sí ìyà igbó ọdẹ, ìwọ a máa yáájú sí mi! Ìwọ ẹbọra olójú-funfun! Gbé ìwé rẹ wá, bí ó bá wù mí èmi á búra, bi kò sì wù mí èmi kò ní í búra. Bí ìwọ bá nà mí ní pàṣán, èmi náà á nà ọ́ ní pàṣán; bí ìwọ bá gbá mi lójú, èmi náà á gbá ọ létí; bí ìwọ bá ṣo mí ní òkúta, èmi náà á sọ ọ́ ní ìdàrọ́, èmi Olówó-ayé, ènìyàn tí ó ju ènìyàn, ọdẹ tí ó jẹ́ olórí ọdẹ. Oníbodè yìí kò tilẹ̀ bìkítà fún bàbá mi. Dípò tí ì bá fi fún bàbá mi lésì ki wọ́n jọ máa sọ̀rọ̀ sí ara wọn, ó rọra gbé ìwé, ó ṣí ibì kan báyìí, ó gbé e sí iwájú bàbá mi, bẹ́ẹ̀ ni onírúurú ẹṣẹ̀ ọmọ aráyé ni wọ́n tò sí ibẹ̀, àti ẹ̀ṣẹ̀ kékeré àti títóbi, ó wí fún bàbá mi pé kí ó búra bí kò bá ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ kan rì nínú wọn. Wò mí, ọ̀rẹ́ mi, gbé ojú sókè, ojú ni ọ̀rọ̀ wà, Ọlọ́run tóbi Lọba, máa ṣọ́ra, máa ṣọ́ra, máa ṣọ́ra kí o tóó máa ṣátátá ọmọnìkejì rẹ, nítorí bàbá mi ni ó máa ń kéde fún gbogbo aráyé wi pé kí wọn kí ó má ṣe dá ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ìyàlẹ́nu ló sì jẹ́ l’ọ́jọ́ náà, nígbà tí òun pàápàá rí i wí p’w ìwà tí òun wí pé kí ènìyàn má ṣe hù wọn-ọnnì ni òun náà pàápàá ń hù, ẹ̀sẹ̀ tí òun wí pé kí àwọn aráyé má ṣe dá ni òun náà pàápàá ń dá, ìrìn tí òun wí pé kí ènìyàn má ṣe rìn ni òun pàápàá ń rìn, ọ̀rọ̀ tí òun wí pé kí àwọn ọmọ aráyé má ṣe sọ ni òun pàápàá ń sọ, ìtìjú pàdé ìtìjú, ní ọjọ́ tí bàbá mi rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn-nnì nínú ìwé oníbodè, níbi tí onítọ̀hún tò wọ́n sí gbàgàgadagba. Háà! Alákọrí kún inú ayé dé ẹnu, ẹ̀rù àwọn ẹlòmíràn ń bà mí, wọ́n á máa kígbe ọmọ-ọlọ́mọ káàkiri, wọ́n á kígbe ní ilé, wọ́n á kígbe ní oko, wọ́n á kígbe ní kọ̀rọ̀, wọ́n á kígbe ní gbangba, wọ́n á kígbe ní ọ̀ọ̀dẹ̀, wọ́n á kígbe ní yàrá, wọ́n dàbí ọkùnrin arẹwà tí ó dára lójú ṣùgbọ́n tí inú rẹ̀ kún fún jẹ̀díjẹ̀dí àti aràn, èérí ẹ̀dọ̀ àti èérí ìfun, àwọn wọ̀nyí kò ní gbòǹgbò rárá bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kígbe kiri pé gbòǹgbò ẹlòmíràn kò tóbi, àfòmọ́ ń pẹ̀gàn ìrókò, ìtàkùn lásán ń pẹ̀ggàn awùsá, ìyẹ́ ń wi pé òkúta kò wúwo – bẹ́ẹ̀ ni ìyẹ́ ń bẹ lójú omi, òkúta ń bẹ ní ìsàlẹ̀ odò. Ọmọ aráyé ń wo ìpàkọ́ ẹlòmíràn, wọn kò jẹ́ wo ìpàkọ́ ara wọn. Ọ̀rẹ́ mi, kíyè sára, má ṣe bá àwọn elékèé péjọ nínú àwújọ wọn, nítorí aṣiwèrè ni wọ́n, ẹnu wọ́n mú bí idà olójú-méjì, ó lágbára bí àáké tí bàbá mi fi ń bẹ́ igi oko, wọ́n a fi ẹnu pa ènìyàn, wọ́n á fi ẹnu ba iṣẹ́ ènìyàn jẹ́, wọ́n á fi ẹnu ti ọmọnìkejì wọn sí inú ibojì: nítorí kí ni ńkọ́? – nítorí èṣù ti gbé àga ìjàngbọ̀n, ó jókkòó pẹ̀lú ayọ́, ó fi ẹ̀hìn tì ní inú wọn, ìgbà tí ibẹ̀ si rọ èṣù lọ́rùn, ó tún gbé ibùsùn wá, ó sún, ó ń han-anrun. Ìgbẹ̀hìn ni kí ìwọ máa wò, nítorí Olódùmarè ń bọ̀ wáá bẹ̀ wọ́n wwò àkókò ni kòì tí ì tó, ojú gbogbo wa ni yóó ṣe. Ìgbẹ̀hìn onírìkíṣí kì í dára, ìṣubú rẹ̀ a sì da bí ìgbà tí ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì méjìlá bá wó lulé lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nítorí òun dàbí ìkuuku tí ó funfun bí i fàdákà níwájú, ṣùgbọ́n tí a dé ibẹ̀ tí ó di òfo. Ìwọ ọ̀rẹ́ mi, nígbà tí Olówó-ayé wo inú ìwé oníbodè, àti búra di ìṣòro. Ọ̀rọ̀ náà kúrò l’ẹ́nu bàbá mi títí, ó sọ ọ́ títí ó fi bí wa, láti ọjọ́ náà wá ni ó sì ti pa á láṣẹ pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe bú ẹnìkejì rẹ̀ lẹ́hìn mọ́, nítorí nínú gbogbo ọmọ ènìyàn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé, kò sí ọ̀kan ṣoṣo tí ó pé nínú wọn. Ṣùgbọ́n bàbá mi kò jẹ́wọ́ níwájú oníbodè, nítorí ọmọ ènìyàn kì í jẹ́wọ́ níwájú ọ̀tá, ìgbà tí ọmọ aráyé bá ti gbé ẹ̀wù ìbàjẹ́ wọ̀ tán, wọ́n á fi ìgbójú bo ara wọn ní àṣírí ìtìjú, ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ á sálọ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn, ohun gbogbo á di jàgídíjàgan. Bàbá mi gbé ìwé sílẹ̀ ó pa òṣé ó wí fún Àǹjànnú-ìbẹ̀rù wí pé òun kì í búra fún ẹnikẹ́ni – gọ́ngọ sọ, ọ̀gọ lẹ́hìn aṣiwèrè, àǹjànnú àti ènìyàn bẹ̀rẹ̀ ìjà, sẹ̀lẹ̀ ṣẹ̀ ní Igbó Olódùmarè, eruku sọ làù lójú ọ̀run, bàbá mi àti ẹbọra oníbodè bẹ̀rẹ̀ ìjàkadì, ìwọ ọ̀rẹ́ mi, nǹkan ṣe!- Àwọn ẹbọra péjọ, àwọn ẹranko péjọ, àwọn ẹyẹ péjọ, àwọn ejò sí lọ́ mọ́ igi. Nítorí ìgbà tí ìjà ńlá yìí ti bẹ̀rẹ̀ ni agogo ti lù káà kiri Igbó Olódùmarè tí onírúurú àwọn abàmì ẹ̀dá ti bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọ, wọ́n wá láti wòran. Àfi àwọn àgbàlagbà ẹbọra ni wọn kò lè rí àyè wá nítorí ìdíwọ́ ilé wọn. Síbẹ̀síbẹ̀ náà pẹ̀lú, àwọn wọn-ọnnì yan aṣojú tí yóò wáá ìròyìn bá wọn. Àwọn ohun ẹlẹ́mìí gbogbo gbo tí wọn kì í jáde lọ́sàn-án ni wọ́n jáde wá wòran, nítorí òkété j;ade, a sì rí òwìwí, bẹ́ẹ̀ ni àdán bá àwọn ẹyẹ wá. Àwọn ẹranko pàtàkì gbogbo tí wọn ń gbé etí ìbodè ni wọ́n jáde nítorí ọ̀ràn yìí, nítorí kìnnìún dúró gẹ́gẹ́ bí alága, àjànàkú sì dúró bí igbákejì, bẹ́ẹ̀ ni ẹkùn wà nínú ẹni tí ń wòran. Ṣùgbọ́n àwọn ẹja kò lè wá, nítorí omi jìnnà sí ojú ìjà náà, bẹ́ẹ̀ ni ẹja tí ó bá kúrò nínú odò, eléyìínì múra ọ̀run alákejì. Ìjà náà pọ̀ gidigidi, nítorí bàbá mi kò yéé ròyìn ọ̀ràn yìí títí ó fi kú. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ti sọ fún ni, Àǹjànnú-ìbẹ̀rù fẹ́rẹ̀ dá bàbá mi nì ẹ̀hìn níbi tí ó ti ń fi ẹ̀hìn rẹ̀ na igi. Ṣùgbọ́n òun náà kò jáfara rárá, nítorí tí ó gbé ẹbọra náà lu inú ìtakùn, ẹ̀gún gún onítọ̀hún ní ẹsẹ̀, ẹbọra sí fi ara bó fẹ́lẹfẹ̀lẹ. Ìjà yìí pẹ́ ki ó tóó tán, nítorí kò sí ẹni tí ó máa mú àwọn oníjà yìí, àwọn tí ó sí dúró níbẹ̀ pẹ̀lú, wọn kò fẹ́ kí ìjà náà tètè pa’ri,nítorí aláràngbọ́ ni Àǹjànnú-ìbẹ̀rù ó sì ti tẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ gbogbo. Ìgbà gbogbo ni òun máa ń fi ìyà jẹ wọ́n, ìgbà tí ìjà bá sì dé láàrin òun àti ìyàwó rẹ̀, bí ẹnikẹ́ni wí pé kí wọn má jà kò ní í gbọ́ sí olúwarẹ̀ lẹ́nu – wọ́n ti sọ ọ́ lórukọ: aláràngbọ́ gbé ẹ̀wù ìtìjú wọ̀, ẹni tí ó bá ń jà tí a dá sí ìjà rẹ̀, a fẹ́ràn rẹ̀ ni. Ìyà jẹ Àǹjànnú-ìnẹ̀rù lọ́jọ́ náà, ẹbọra sì bẹ̀rẹ̀ sím i hẹlẹhẹlẹ. Ìhìn náà kò dùn ní ẹnu mi, wò mí, ọ̀rẹ́ mi ìbá ṣe pé ìwọ gbọ́ ọ láti ẹnu bàbá mi ni, ẹnu ìbá yà ọ́ gidigidi – nítorí wọ́n fi ẹsẹ̀ hú gbòǹgbò, wọ́n tẹ igi dá, wọ́n fa ew’wko tu, gìrìgìrì ẹsẹ̀ wọn sì dàbí ìlú ìbẹ̀ǹbẹ́, ara wọ́n tutù bí ara ẹni tí òjò ń pa; ṣùgbọ́n nígbà tí ó pẹ́ wọ́n tú ọwọ́, wọ́n jókòó, wọ́n ń simi. Ibi tí wọ́n ti ń simi yìí, ìyàwó oníbodè gbé oúnjẹ wá fún ọkọ rẹ̀ ó sì bu omi sí i. Nígbà tí ìyàwó Olówó-ayé àfẹ́sọ́nà tí ó ti sọ ara rẹ̀ di ẹyẹ náà ri èyí, ó yípadà ó ddi ènìyàn, ó mú oúnjẹ ni inú àpò ó fí í fún ọkọ rẹ̀ tuntun, ó si wí pé ‘Gba eléyìí, jẹun dáadáa, má ṣe jẹ́ kí inú run ọ́, ọkọ kì í ju ọkọ lọ.’ Báyìí ni àwọn méjèéjì ṣe ti wọ́n tọ́jú ọkọ wọn, nítorí ìtọ́jú ọkọ ni pàtàkì iṣẹ́ obìnrin tí ó ní ọkọ. Ìgbà tí inú tọkọtaya bá dùn ni wọ́n tóó lè gbádùn ọmọp wọn. Sùúrù ni bàbá àti ìyá aǹfààní, òmùgọ̀ ènìyàn ní í wí pé sùúrù òun pọ̀ jù nítorí sùúrù kò ní òpin. Kí tọkọtaya mọ̀ pé bí sùúurù tì àwọn bá mú fún ara àwọn lónìí bá ju ti àná lọ, àwọn yóò ní owó, àwọn yóò ní ọmọ, àwọn yóó sì ní àlàáfìá tí í ṣe olùborí owó àti ọmọ. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn máa rẹ̀ ọ jẹ, mú sùúrù fún wọn, ṣé ìwọ mọ̀ nínú ara rẹ pé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìṣubú ni eléyìínì. Bí ènìyàn bá rẹ́ ọ jẹ, tí ìwọ sì ṣe bí ẹni pé ìwọ kò tilẹ̀ mọ̀, ìwọ ti gbé eléyìínì sí inú ìkòkò gbígbóná, èrí-ọkàn rẹ̀, yóò sì máa ko iná mọ́ ọn. ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá mú sùúrù tó, tí ìwọ ń bá olórí-burúkú ènìyàn bínú pọ̀, òun óò kó ìwà òmùgọ̀ ràn ọ́, òun á sì mọ̀ pé òun ṣe dùn ọ́, òun á gbé ẹ̀wù ìgbéraga wọ̀ sí èjìká, bẹ́ẹ̀ ni òun kò ní ìrètí àti lọ sí iwájú mọ́ ní tirẹ̀, nígbà tí òun bá si kkó ìbànújẹ̀ bá ọ lónìí, a ṣe bẹ́ẹ̀ dí ọ lọ́wọ́ ìlọsíwájú ẹ̀hìn ọ̀la. Nígbà tí bàbá mi àti ẹbọra náà simi tán, tí wọ́n jẹun ìyàwó wọn tán, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí ìjà wọn. Bẹ́ẹ̀ ni èéfin ń rú jáde láti agbárí ẹbọra yìí tí ẹ̀rù rẹ̀ sì ba ènìyàn gidigidi. Ṣùgbọ́n kí wọn tóó bẹ̀rẹ̀ ìjà ní ẹ̀ẹ̀keejì ni àwọn nǹkan Igbó Olódùmarè ti pejọ́ bámúbámú. Ọlọ́run tóbi lỌba, ojú bàbá mi rí nǹkan, Oówó-ayé pọ̀ lọ́kùnrin. Ìjà náà sì túbọ̀ ń le sí i, nítorí ọ̀ràn náà ń fẹ́ẹ́ bọ́ sí ìtìjú, nítorí ìyàwó àwọn méjèéjì bi wọ́n dúró tí wọ́n ń wo ọkọ wọn. Ìwọ akọ̀wé mi, ǹjẹ́ o kò rí i pé ó yẹ kí ènìyàn múra sí irú ìjà bẹ́l ńdan? ẹni tí ó ń fẹ́ẹ́ gbé ni lúlẹ̀ ìyàwó ẹni o kò rí i pé eléyìínì ń fẹ́ẹ́ dójú ti ni ńdan? Ìgbà tí ìjà bá lọ tán ìtìjú kò ní í lọ, olúwaarẹ̀ kò ní í gbọdọ̀ ṣe gbólóhùn aṣọ mọ́, ìyàwó á máa pa guurú sí ọkọ: bẹ́ẹ̀ ni ìgbà tí ó bá ń di pé ìyàwó ń gbá ọkọ létí, tí ó ń ta ọkọ ní ìpá, tí ọkọ ń sá wọ iyàrá, tí ọkọ ń gba ọ̀nà ẹ̀hìnkùnlé, tí obìnrin ń lọ aṣọ mọ́ ọkùnrin lọ́rùn, tí ìyàwó ń yí àṣẹ ọkọ padà, tí ìyàwó ń lọ sí òde tí kò sọ fún ni mọ́, tí a béèrè ibi tí ìyàwó ti ń bọ̀ ti ìyàwó ń mọ́ ni lójú, ńjẹ́ o kò rí i pé nǹkan ń dé bẹ́ẹ̀ ńdan? Bẹ́ẹ̀ ni bí ìyàwó bá ti rí ọkọ fín, nǹkan báwọ̀nyí kò ní ṣàì máa ṣẹlẹ̀ láàrrin òun àti ọkọ. Nítorí èyí, ní ọjọ́ ìjà Olówó-ayé pẹ̀lú oníbodè, ìdàrúdàpọ̀ gba inú igbó kankan. Èyí tí ó túbọ̀ wáá ba nǹkan jẹ́ ni ìlù ìbẹ̀ǹbẹ́ àti gángna tí àwọnn ẹbọra Igbó Olódùmarè kó wá sí ojú ìjà kí ìjà tóó bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, àwọn ẹbọra ń lu ìyá ìlù, ìnàkí àti ọ̀bọ ń lu omele, nígbà tí wọ́n sì béèrè orúkọ bàbá mi tí ó sọ fún wọn ni wọ́n ti tẹ gọ̀ǹgọ́ mọ́ ojú ìlú ti wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: Olówó-ayè, dìgbò lù ú, kọlù ú, dìgbò lù ú, kọlù úu, ọmọ Akọ̀wédìran, ọmọ Akọ̀wédìran, Olówó-ayé, Olówó-ayé, o kò lè ṣe bí bàbá rẹ ńdan? O kò lè ṣe bí bàbá rẹ ńdan? Olówó-ayé, Olówó-ayé, ara kò le bí? Ara kò le bí? Ṣé kò sí ǹkan? Ṣé kò sí ǹkan? Olówó-ayé, Olówó-ayé, kùmọ̀ ńlá ń bẹ lápá ọ̀tún, ẹrù pàṣán ń bẹ lápa òsì, ìṣubú Àǹjànnú ń bẹ ní ibi gegele òkúta. Olówó-ayé, Olówó-ayé, mú ẹbọra lápa, mú ẹbọra lẹ́sẹ̀, gbé ẹbọra kúrò ní ilẹ̀ tán pátápátá. Olówó-ayé, ojú ẹbọra ń wò ọ́, ojú ènìyàn ń wò ọ́, gbogbo alààyè ló pé sí inú Igbó Olódùmarè bámúbámú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Báyìí ni ìlù ń dún kíkankíkan tí àwọn méjéèjì ń mí hẹlẹ, tí ilẹ̀ ń mì tìtì, tí gbogbo igbó sì dákẹ́ minimini. Nígbà tí ó ṣe, Àǹjànnú-ìbẹ̀rù gbé ẹsẹ̀ ọ̀tún bàbá mi kúrò ní ilẹ̀ tán pátápátá, ó sì ń gbé e lọ sí ibi èjìká, bàbá mi fi ẹsẹ̀ osì ti ilẹ̀ bí ẹbọra náà ti ń tì í lọ sí ibi kòtò kí onítọ̀hún baà ṣubú sí inú kòtò kí ó kún inú kòtò bámúbámú - ṣùgbọ́n eléyìínì kò ṣeé ṣe; nítorí kí òun tóó ti bàbá mi dé inú kòtò, bàbá mi ti gba ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún sílẹ̀ ó sì ti fi méjèéjì ti ilẹ̀, nígbà tí Àǹjànnú-ìbẹ̀rù si bẹ̀rẹ̀ báyìí tí ó gbá bàbá mi kúrò ni ilẹ̀ tán pátápátá tí ó sọ ọ́ sí iwájú pẹ̀lú agbára, ẹsẹ̀ ni bàbá mi fi ti ilẹ̀ tí ó dúró gbọnin, nígbà tí ó sì wọ ẹbọra náà lójú ó bú sí ẹ̀rín ó wí pé, ‘Ẹ̀hìn ológbò kì í balẹ̀, èèwọ̀ ni – gbogbo àwọn iwin sì pariwo. Lẹ́hìn èyí ni bàbá mi bẹ̀rẹ̀ tí ó gbé oníbodé lé èjìká tí ó sì ń gbé e lọ ní ìrètí àti na ẹ̀hìn rẹ̀ mọ́ òkúta kọ̀bìtì kan tí ń bẹ ní ẹ̀bá ibẹ̀ ṣùgbọ́n kí òun tóó dé ibi òkúta yìí, onítọ̀hún ti tàkítí ọ̀bọ láti èjìká ó sí bọ́ sí ilẹ̀ ó dùró gbọnin - awọn iwin sì lu ìlù ayọ̀ láti fi bá oníbodè yọ̀ wí pé ó kú oríire. Nígbà tí ó ṣe, inú bí ẹbọra yìí ó sì pinnu àti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹbọra, ó yí padà ó di kìnnìún. Ìgbà tí bàbá mi náà kì í sì í ṣe ọmọdé ọdẹ, òun náà hu ìwà àgbàlagbà, ó mú èèso igi tí ẹ̀gbọ́n ìyàwó rẹ̀ fún un, ó sọ ọ́ sí ẹnu, òun náà sì yípadà ó di kìnnìún, kìnnìún sì bẹ̀rẹ̀ sí bá kínnìún jà, gbogbo igbó ń bú ramúramú: àwọn ẹbọra Igbó Olódùmarè sì �� sáré kiri. Nígbà tí ó ṣe, ẹbọra yí padà ó di òjòlá, Olówó-ayé náà yí padà ó di òjòla, òjòlá sì bẹ̀rẹ̀ sí bá òjòlá jà, gbogbo igbó ń ké bí ẹran, ìjàngbọ̀n sì gba Igbó Olódùmarè kan-kan. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ si yí padà sí onírúurú ǹkan títí wọ́n fi di ejò ọkà. Ṣùgbọ́n kí Àǹjànnú-ìbẹ̀rù tóó yí padà kúrò nínú èyìínì, Olówó-ayé yí padà ó di erin, nígbà tí erin sì fi ọwọ́-ìjà rẹ̀ mú ọká ni àtàrí, ó fọ́ ọ yánmúyánmú. Bẹ́ẹ̀ ni bàbá mi ri ẹ̀hìn oníbodè yìí, ìjà náà si di òwe káà kiri ayé ni àkókò ìgbà náà. Síbẹ̀síbẹ̀, títí di oní olónìí, àwọn àgbàlagbà kì í yéé sọ̀rọ̀ ìjà ibodè Igbó Olódùmarè yìí, nítorí ibẹ̀ ni àwọn oníjà gbé di ọká, tíwọ́n di erè, ti wọ́n sì di àjànàkú bàbá ẹranko. Àsẹ̀hìnwá-àsẹ̀hìnbọ̀ bàbá mi yípadà ó di ènìyàn, ṣùgbọ́n a kò gbúròó Àǹjànnú-ìbẹ̀rù mọ́, ó ti kú pátápátá. Bàbá mi sì mú ejò ọká náà ó dá iná sun ún, ó sì kó eérú rẹ̀ dànù sí orí ààtàn, ṣùgbọ́n nígbà tí òjò rọ̀ àgbàrá òjò gbá apá kan rẹ̀ sí inú odò kékeré kan, níbẹ̀ ni eérú náà sì ti yípadà tí ó di ẹja olóró kan títí di òní yìí, ní ọjọ́ tí mo bá rí ẹja náà, ìwọ ọ̀rẹ́ mi, n ó fi hàn ọ́. Èyí tí kò lọ sí inú odò nínú eérú náà pẹ̀lú yìpadà ó di àkeekèé, n ó sì fi irú àkeekèé náà hàn ọ́ ní ọjọ́ tí mo bá rí i. Ṣùgbọ́n ọ̀kánkán ibi tí wọ́n ti ja ìjà yìí kò hu koríko mọ́, dípò èyí, àwọn ará Igbó Olódùmarè kọ́ ilé kan sí ibẹ̀, nínú èyí tí oníbodè tuntun ti wọ́n yàn ń gbé, oníbodè yìí kò sì dàbí ti àtijọ́ọ́, nítorí ó fẹ́ràn ènìyàn ó sì fẹ́ràn ẹranko, ó fẹ́ràn aráyé, ó sì fẹ́ràn ará ọ̀run. Ṣùgbọ́n kí ni ìgbẹ̀hìn ìjà yìí jẹ́ fún bàbá mi? – Ìgbẹ̀hìn rẹ̀ dára gidigidi. Ilé ti wọ́n kọ́ fún oníbodè náà jẹ́ ilé òkúta, wọ́n sì kọ ọ̀rọ̀ nípa bàbá mi sí ara rẹ̀ lẹ́hìn òde. Ohun ti wọ́n kọ sí ibẹ̀ ni ìwọ̀nyí: ILÉ YÌÍ WÀ NÍ ÌRÀNTÍ ẸNI Ọ̀WỌ̀ OLÓWÓ-AYÉ, ọ̀kan NÍNÚ Àwọn ọmọ ÈNÌYÀN TÍ Ó WÁ SÍ IGBÓ OLÓDÚMARÈ LÁTI ṣe ọdẹ. ÌFORÍTÌ NI OLÓWÓ-AYÉ FI ṣẹgun ÀǸJÀNNÚ-Ìbẹ̀rù TÍ Í ṣe ONÍBODÈ IGBÓ OLÓDÙMARÈ. NÍTORÍ ÌDÍ ÈYÍ, ẹnikẹ́ni TÍ KÒ BÁ NÍ ÌFORÍTÌ KÒ Gbọdọ̀ Lọ SÍ IGBÓ YÌÍ Lọ ṣe ọdẹ LÁÉLÁÉ. NÍTORÍ KÒ SÍ ẹni TÍ KÒ GBÉ ẹrù ÌSÒRO Tirẹ̀ LÉ ÈJÌKÉ, ẹrù Ìṣòro TI ẹnì KAN KÒ BÁ TI ẹni KEJÌ MU, ṣùgbọ́n Pẹ̀LÚ ÌFORÍTÌ, Ọlọ̀run ỌBA ṣetán ÀTI Sọ OLÚKÚLÙKÙNÍ ẹrù Ìṣòro Tirẹ̀ Kalẹ̀ PÁTÁPÁTÁ. Báyìí ni wọ́n kọ ìwé sí ẹ̀gbẹ́ ilé náà tí orúkọ bàbá mi sì wà ní ibẹ̀ títí di oní. Ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ni ó jẹ́ fún ni pé onibodè tuntun náà kò pẹ́ ní ibẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí gẹ́gẹ́ bí ó ti ríní àárin àwọn ènìyàn ni ó rí nì ààrin àwọn ẹbọra, nítorí oníbodè yìí kò lo àwọn ẹ̀dá wọnọnnì ni ìlò ẹrù, tí kò fi wọ́n sí ipò ìwọ̀fà, tí ó pè wọ́n ní ọmọlúwàbí, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn ṣiré, wọ́n fi ọwọ́ pa idà rẹ̀ lójú, nítorí bí ó ti wà ní àárin ènìyàn náà nì ó rí ní ààrin àwọn ẹbọra, àwọn ẹni ìwọ̀sí kan wà lórí ilẹ̀ ayé tí wọn kò jẹ́ lo àǹfààní tí Ọlọ́run Ọba fún wọn, àwọn wọ̀nyí ni àwọn afooresúniíṣe, bi o bá yẹ́ wọn sí, tí o lò wọ́n bí ènìyàn, dípò kí wọ́n máa fẹ́ ọ tọkànktọkàn, ìwà àrífín ni wọn yóò maa hù sí ọ: àwọn wọ̀nyí dàbí igi ńlá tí ó wó si ojú ọ̀nà mọ́tò, tí kò jẹ́ kí mọ́tò kọjá mọ́, nítorí ẹni tí ó bá bá wọn lò lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, wọn kò ní jẹ́ kí olúwaarẹ̀ fẹ́ẹ́ máa hu ìwà rere sí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́hìn mọ́. Ìgbẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ inú ayé ni àwọn wọn-ọnnì jẹ́, kí Olódùmarè gba ọmọ aráyé lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ mi, bí ẹnikẹ́ni bá ń yẹ́ ọ sí ìwọ náà máa yẹ́ olúwaarẹ̀ sí, bí ó bá ń gbé ọ ga ìwọ náà túbọ̀ máa gbé e ga, bí ènìyàn ńlá bá ń lò ọ́ bí ẹnìkejì ara rẹ̀ túbọ̀ gbé e ga, tó bẹ́ẹ̀ tí yòó fi mọ̀ pé ìwọ kò rí òun fín. Àwọn ẹni tí kò bá ṣe ìwọ̀nyí jẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn tí ń bọ̀ lẹ́hìn, nítorí wọ́n fi oore sú àwọn alágbáraṣe, àwọn alágbára á sì máa ti ìtorí bẹ́lẹ̀ hu ìwàkíwà fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn wọn; nítorí ki ni ńkọ́, nítorí wọ́n á wí pé bi àwọn b�� hu ìwà dáradára àrífín ni èrè àwọn. Àwọn tí ń hùwà báyìí jẹ̀bi ènìyàn dúdú, wọ́n jẹ̀bi ènìyàn funfun, wọ́n jẹ̀bi àwọn tí kò dúdú tí kò funfun, wọ́n sì ń fi Olódùmarè si ipò tí Òun ìbá fi wi pé ‘Èmi ìbá mọ̀ ki n dá àwọn wọ̀nyí ní ẹranko ki wọ́n máa jẹ ewéko inú igbó kiri, kí àwọn ọdẹ sì máa fi ìbọn wá wọn ká láti ìrandíra wọn. Ṣùgbọ́n Olódùmarè kò jẹ́ sọ báyìí, nítorí aláàánú ni Òun í ṣe. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bú oníbodè nì káà kiri pé òun ń ba àwọn èrò ọ̀nà jẹ́, òun kò fi ìyà jẹ wan tó bí ó ti yẹ kí ó ṣe, òun ń jẹ́ kí àwọn èrò rí oníbodè Igbó Olódùmarè fín, wọ́n sí wáá bẹ̀rẹ̀ sí yin Àǹjànnú-ìbẹ̀rù fún ìyà ńlá gboggbo tí ó ti fi ń jẹ wọ́n. Nítorí ìdí èyí, oníbodè tuntun yìí yí ìwà rẹ̀ padà, ó bẹ̀rẹ̀ sí hu ìwà tí Ọlọ́run Ọba kò dá mọ́ ọn, àsẹ̀hìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìwà náà le ju ti Àǹjànnú-ìbẹ̀rù lọ. Nígbà tí àwọn ẹ̀dá wọn-ọnnì sì gbé àjàgà tí í ó wúwo, tí wọ́n sì ru ẹ̀rù tí kò fúyẹ́, wọ́n di rìkísí ńlá mọ́ oníbodè, títí onítọ̀hún fi fi iṣẹ́ sí ilẹ̀ tí ó wá si Igbó Irúnmọlẹ̀ tí ó ń gbé ibẹ̀ di bí mo ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Ọba wí pé Igbó Irúnmọ́lẹ̀ dẹ ẹ̀dá náà lọ́rùn ju Igbó Olódùmarè lọ. Nítorí nígbà tí èmi pàápàá lọ ṣe ọdẹ nínú Igbó Irúnmọ́lẹ̀ mo rí i pé òun kò gbé ilé ilẹ̀ bí i ti Igbó Olódùmarè mọ́, mo bá a lórí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì mẹ́ta tí ó dúró lé orí ara wọn. Fi eléyìí ṣe àríkọ́gbọ́n, ìwọ ọ̀rẹ́ mi, bí ènìyàn le púpọ̀ ọmọ aráyé á bú u, bí ènìyàn rọ̀ púpọ̀ ọmọ aráyé á bú u, ṣùgbọ́n bí ènìyàn bá wà ní ìwọ̀n-túnwọ̀nsì, bí olúwaarẹ̀ tilẹ̀ gba èébú àwọn òmùgọ̀ inú ayé, olúwaarẹ̀ yóò ní iyì lójú àwọn ọlọgbọ́n, òun kò sì ní gba èébú Ọlọ́run Ọba. Akọ̀wé mi, o kú iṣẹ́ o, jẹ́ kí n máa bá ìtàn Olówó-ayé lọ, nítorí eléyìínì ni ọ̀rọ̀ pàtàkì tí à ń sọ lọ́wọ́ kí ó tóó di pé mo dà ọ̀rọ̀ ti oníbodè tí ó dípò Àǹjànnú-ìbẹ̀rù sílẹ̀. Ibi tí mo bá ìtàn náà dé ní ẹ̀ẹ̀kan ni ibi tí wọ́n tí kọ orúkọ bàbá mi sí ẹ̀gbẹ́ ògiri, ti wọ́n sọ̀rọ̀ rẹ dáradára. Dájúdájú kò ní ṣàì yà ọ́ lẹ́nu pé eléyìínì náà ni wọ́n ṣe fún bàbá mi mọ, òótọ́ ni, wọn ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà tí bàbá mi ti rí ẹ̀hìn ẹbọra náà tán, gbogbo àwọn ará Igbo Olódùmarè pa èrò pé kí wọ́n mú un lọ sí ọ̀dọ̀ oba wọn: wéré, wọ́n ti bọ́ ẹ̀wù ọdẹ kúrò ní ọrùn bàbá mi wọ́n sì gbé ẹ̀wù agbádá àrán ńlá kan bọ̀ ọ́ lọ́rùn, wọ́n fún un ní ṣòkòtò àrán, wọ́n sì dé e ní fìlà àràn tí ó rí gòǹgò bí adé tí wọ́n fi góòlù ṣe ọ̀ṣọ́ sí lára tí ó ń dán yinrinyinrin, bàtá idẹ ni wọ́n fi bọ̀ ọ́ ní ẹsẹ̀, òrùka góòlù win wọ́n fi sí i ní ọwọ́, ẹ̀wọ̀n góòlù ni wọ́n fi bọ̀ ọ́ ní ọrùn. Lẹ́hìn èyí, wọ́n wáá fi ọ̀pá ìlẹ̀kẹ́ lé e ní ọwọ́ wọ́n sì mú ìyàwó àfẹ́sọ́nà rẹ̀ wọ́n ṣe é ní ọ̀ṣọ́ láti orí dé àtẹ́lẹsẹ̀, ara eléyìínì mọ́ tónítóní bí òṣùmàrè àwọsánmọ̀, eyín obìnrin náà sì dàbí òòrùn ọ̀án gangan. Àfi obìnrin náà ni ó b á bàbá mi mu nínú ọlá ńlá Igbó Olódùmarè yìí, bẹ́ẹ̀ ni, èmi ni mo wí fún ọ, bàbá mi dára lọ́kùnrin, ẹ̀gàn ló kù; kì í ṣe nítorí pé ó jẹ́ bàbá mi ni mo fi sọ bẹ́ẹ̀, àwọn ará ìlú wa gan-an ní ẹni tí ń fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe orin kọ, wọn a máa wí nípa tirẹ̀ pe’: ‘Olówó-ayé, arẹwà lọ́kùnrin.’ Ìgbà tí wọ́n ṣe àwọn méjéèjì ní ọ̀sọ́ báyìi’tán wọ́n gbé wọn sí inú kẹ̀kẹ́ wọ́n si ń yí wọn lọ. Ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ náà nínú igbó ńlá yìí, àwọn ẹranko àti ẹyẹ ń ké kábíyèsí, àwọn igi gbogbo bẹ̀rẹ̀ sí tẹ orí wọn ba, àwọn ìtàkùn bẹ̀rẹ̀ sí kí Olówó-ayé bí òun àti ìyàwó rẹ̀ ti ń ṣe fáàrí nínú ọlá ńlá wọn. Nígbà tí wọ́n sé ààfin ọba Igbó Olódùmarè ọ̀rọ̀ pa èsì jẹ. Nítorí ààfin náà dára púpọ̀, ó dára ju nǹkan tí ẹnu máa sọ. Nígbà tí wọ́n dé ita ibẹ̀, ọba pàápàá wà nínú ilé, nígbà tí ó sì yọ sí bàbá mi, ẹ̀rù ba bàbá mi. Wéré, ó dọ̀bálẹ̀ ó bu erùpẹ̀ lé orí, ó ké kábíyèsí ó sì yẹ́ ẹ sí bí ọba. Lẹ́hìn eléyìí ọba náà dáhùn ó wí pé: Ńjẹ́ ìwọ ni ọkùnrin náà tí ó pa Àǹjànnú-ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀? Òun sì dáhùn ó wí pé, ‘Kábíyèsí, èmi ni.’ Ọba náà tún ṣe ìbéèrè, ó ní, ọ̀nà wo ni ìwọ gbà tí ìwọ fi pa Àǹjànnú-ìbẹ̀rù? Kí ni ìwọ sì gbẹ́kẹ̀lé tí ọ̀ràn náà fi ṣeé ṣe? Bàbá mi náà sì tún fèsí pẹ̀lú, ó ní, Kí Ọlọ́run bùn yín lẹ́mìí, ọ̀nà tí mo gbà kò ju kékeré lọ: mo pinnu àti bá ẹbọra náà jà, mo bẹ̀rẹ̀ ìjà, mo fi ara da ìṣòro ìjà, mo sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Ọba tí Ó dá mi. Kábíyèsí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájú láti òní lọ pé, ẹni tí ó bá ń fẹ́ẹ́ ṣe nǹkan rere, tí ó fi ara da ìṣòro tí ń bẹ nínú nǹkan rere, tí ó sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Ọba eléyìínì kò ní sí láàárin àwọn èrò ẹ̀hìn láéláé. Ọba yìí sì tún dáhùn, ó ni, Ta ni bàbá rẹ? Bàbá mi náà sì tún fèsì ó wí báyìí pé, Kábíyèsí, Akọ̀wédìran ni. Ọba sì tún béèrè, ó ní, Ńjẹ́ ìwọ ti ní obìnrin? Bàbá mi náà sì dáhùn, ó wí pé: mo ni àfẹ́sọ́nà kan, òun náà ló sì jókòó ti mí nínú kẹ̀kẹ́ yìí. Lẹ́hìn náà ni ọba yìí kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, ìwọ alágbára ọkùnrin, ìwọ ọmọ ènìyàn, níhìn-ín ni n ó ti ṣe ìgbéyàwó fún ọ, ọgbọ́n ń bẹ ní àtàrí rẹ, n óò gbé ìyàwó fún ọ nígbà tí ó bá tó oṣù méjì tàbí mẹ́ta lónìí, n óò rànṣẹ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ mi jákèjádò inú igbó, n ó sì ránńṣẹ́ sí àjùlé ọ̀run kí wọ́n wáá ṣe àríyá nítorí ọ̀ràn rẹ. ẹ̀yin ọmọ mi gbogbo, mo fẹ́ kí ẹ fi í sí ọkàn láti òní lọ pé, kò sí nǹkan tí ń bẹ ní orí ilẹ̀ ayé tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣe, ẹni tí ó bá ń fẹ́ẹ́ di olówó lè di olówó, ẹni tí ó bá ń fẹ́ẹ́ di ènìyàn pàtàkì lè di ènìyàn pàtàkì, ṣùgbọ́n ọ̀lẹ tí kò fẹ́ẹ́ jìyà tí ó sì ń fẹ́ẹ́ di ènìyàn pàtàkì yóò máa wà láàrin àwọn èrò ẹ̀hìn láéláé. Ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó ń kọ́ iṣẹ́ lónìí, tí ó ń múra àti mọ iṣẹ́, tí ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Ọba tí Ó dá a, kí eléyìínì má ṣe bẹ̀rù, kí eléyìínì máa rọ́jú ǹṣó, bí òun kò tilẹ̀ rí agolo gaàrí wà mu, tí òun kò mu ju ṣíbí ẹ̀kọ kan, tí ọ̀gá ń ṣe ìgbọ̀nsè tí ó ń da ìgbọ̀nssẹ̀ nù, tí ọ̀gá ń wọ ẹ̀wù àrán tí òun ń wọ àkísà, kí òun náà mọ̀ pé òun ń bọ̀ wáá rí ìgbéga ẹ̀hìn ọ̀la. Àwọn nǹkan wọn-ọnnì tí ó ti ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọ̀dọ̀, ẹlòmíràn ń bọ̀ wáa ṣe é lọ́dọ̀ òun. Òótọ́ ni mo sọ, nítorí irọ́ kò yẹ ọmọ ènìyàn, irọ́ kò yẹ ọmọ ẹbọra. Ẹ mù Olówó-ayé, ẹni tí ó gba Igbó Olódùmarè lọ́wọ́ Àǹjànnú-ìbẹ̀rù, ẹ wẹ̀ ẹ́, \w wọ̀ ọ́ ni ṣòkòtò, ẹ ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ tí ó ju ìwọ̀nyí lọ. Ẹ mú òun àti ìyàwó rẹ̀ àfẹ́sọ́nà lọ sí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì dídára tí ń bẹ nínú ààfin mi lọ́hùn-ún nì, ibẹ̀ ni kí ó máa gbé, nígbà tí ó bá ṣe díẹ̀ sí i mò ń bọ̀ wàà gbé ìyàwó fún ọmọ akọ̀wédìran. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tí wọ́n sí tọ́jú bàbá mi tí wọ́n sì fi ìyàwó rẹ̀ tì í, tí wọ́n jọ ń gbé fún oṣù mẹ́ta kí ó tóó di pé ọba gbéyàwó fún wọn. Láàárin oṣù mẹ́ta yìí bàbá mi jẹun ó sanra, ẹ̀hin ọrùn rẹ̀ sì rì kọ̀- ǹgbẹ̀- kọǹgbẹ. Kí ó tilẹ̀ tóó di pé bàbá mi fi ayé sílẹ̀, kò sí ọjọ́ náà tí ó máa sọ ìtàn yìí fún wa tí ẹ̀rín kì í pa ni. Òun a máa wí báyìí pé: Mo jẹun ikùn mi rí ringingin bí ikùn ọmọ ẹyẹ, ikùn ńlá tí ó lé dodo sá wọ inú ilé lọ, ìbàdí mi tóbi ó rí jọ̀bọ̀tọ̀jọboto, ẹnu ọ̀nà kékeré kò gba ìyàwó mi mọ̀, nítorí ikùn ẹsẹ̀ rẹ̀ tóbi ju òpó ilé lọ, ìbàdí rẹ̀ sì tó ẹrù géńdé mẹ́fà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀hìn ọrùin rẹ̀ tóbi tó ti ènìyàn mẹ́jọ. Òun pàápàá sì ti yí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ padà, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni òun ń gbé ẹsẹ̀ bíí mààlúù tí ń jẹ koríko, bẹ́ẹ̀ ni òun kò hùwà bí ènìyàn kékeré mọ́, ó ń hùwà bí ìyàwó ènìyàn jàǹkàǹjankan. Àwọn ọlọ́lá kì í fẹ́ẹ́ rìn ìrìn ẹni lásán, olówó kì í fẹ́ẹ́ rin ìrìn tálákà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn obìnrin fẹ́ràn fáàrí gidigidi. Ẹ̀gbọ́n ìyàwó mi náà yí padà pẹ̀lú, nítorí ojú òun náà tutù bí ọ̀jẹ̀lẹ́ ewé òroǹbó, ara rẹ̀ si mọ́ bí ara ọmọ tí a bí ní ìjẹta, nítorí gbogbo wa ni a jẹ óunjẹ tí ó gbádùn, a jẹ ọbẹ̀ tí ó níláárí, a jẹ apá ẹran, a jẹ itan ẹran, a jẹ ẹ̀dọ̀, a jẹ iwe, a sì jẹ gògòńgò ọ̀nà ọ̀fun. Báyìí ni bàbá mi máa ń sọ nígbà tí ó bá sọ ìtàn náà fún wa, gbogbo wa á sì máa rẹ́rìn-ín, gbogbo wa á máa tàkìtì, gbogbo wa á máa yí ní ilẹ̀ kiri. Ìgbà tí ó di ọjọ́ ígbéyàwó bàbá mi, àríyá ńlá gba Igbó Olódùmarè kankan. Onírúurú oúnjẹ ni ó pé sí ààfin ọba, iyán pẹ̀lú ọbẹ̀ ìlá àti ẹran, ìrẹsì àti òróró ẹ̀gúsí tí wọ́n ti sè pẹ̀lú àlùbọ́sà àti ata. Ọkà àti àkàṣù ẹ̀kọ pẹ̀lú ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ tí ó kún fún ẹran. Ẹ̀wà pẹ̀lú ẹja wẹẹrẹ àti edé tí wọ́n pa láti inú òkun tí wọ́n sì ti yan tí ó gbẹ tọọli ni wọ́n sè pọ̀ tí wọ́n gbé ìwọ̀nyí sílẹ̀ kítikìti. Dùǹdù kò jámọ́ nǹkan kan bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún dòdò lọ́jọ́ ìgbéyàwó yìí. Bẹ́ẹ̀ ni a kò lè ka àwọn oúnjẹ ayé ìwòyí, àwọn bíi bọ́tà àti búrẹ́dì, àti onírúurú àkàrà òyìnbó títí kan bisikíìtì òde òní tí àwọn ọlọ̀gbọ́n obìnrin fi àgbọn àti iyọ̀ oyìnbó ṣe. Ìlùi ìbẹ̀ǹbẹ́ àti bàtá, ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ àti kìibótó, gòjé àti bóló,àti onírúurú àwọn ìlù míràn àti ti ènìyàn dúdú àti ti ènìyàn funfun; gbogbo ìwọ̀nyí ni ó pé sí ibi àríyá náà, ọjọ́ ńlá ni. Ṣùgbọ́n ó dùn mí láti sọ fún ọ pé pẹ̀lú ìjà ni wọ́n fi túká ni ibi àsè náà, nítorí ọ̀tọ̀ ni wọ́n kó àwọn ẹranko sí tí wọ́n sì tẹ́ teburu fún wọn. Kìnnìín ni alága, àjànàkú ni igbá kejì, àwọn ẹranko kéékèèkéé sì ni ni agbáwo. Ibi tí ìjà náà ti bẹ̀rẹ̀ ni èyí: ìgbà tí kìnnìún bá béèrè nǹkan kan tí àgbọ̀nrín tí ó jẹ́ olórí agbáwo bá sì ń fi nǹkan náà fún un, a bẹ̀rẹ̀ si í ha àgbọ̀nrín ni èékán a sì máa fà á mọ́ra bí ẹni pé ó ń fẹ́ẹ́ pa á jẹ, a wí pé òun ń bá àgbọ̀nrín ṣiré; nígbà tí ó ṣe, ara àgbọ̀nrín kò gbà á mọ́ ó sì fi kìnnìún sun ọkọ ìyàwó, ọkọ ìyàwó sì bá alága náà wí. Bákàn náà sì ni lọ́dọ̀ àwọn ẹyẹ, Ògòǹgò baba ẹyẹ tí wọ́n pè láti Igbó Irúnmọlẹ̀ pé kí ó wáá ṣe alágá kò rí àyè wá nítorí ìdíwọ́ ilé. Àṣádì ni ó sì ṣe alága dípò rẹ̀. Àwọn ohun ọ̀sìn tí wọ́n pè láti ilé kò lè wá wọ́n sì yan àwọn àgbébọ̀ adiẹ̀ mẹ́fà gẹ́gẹ́ bí aṣojú wọn. Ìgbà tí àṣádì bá sì fi ibi tí ó jókòó sí sílè òun a wá sí ọ̀dọ̀ àwọn àlejò mẹ́fà yìí a bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ pa àgbébọ̀ mẹ́fà lára a wí pé òun ń bá wọn ṣiré. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí hu ìwà àgbàbàgebè pẹ̀lú, òun a tọrọ àyè lọ́wọ́ kìnnìún ti ó jẹ́ alága, a wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹyẹ a bẹ̀rẹ̀ sí wo ojú àwọn adìẹ̀ – ìwà burúkú gbáà ni. Ṣùgbọ́n àsẹ̀hìnwá-àsẹ̀hìnbọ̀ ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ mu ọtí yó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe réderède, Àjànàkú bẹ̀rẹ̀ sí wó igi lulẹ̀, kìnnìún bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ẹranko, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ pa ọ̀kan nínú àwọn àgbébọ̀, Àṣádì ń lé àwọn ẹyẹ kiri. Níkẹhìn inú bí ọkọ ìyàwó ó sì lé gbogbo wọn lọ. Nígbà tí àwọn iwin ń bọ̀ wá sí ibi àsè yìí, ẹ̀rù ba ènìyàn gidigidi: nítorí kí ni ńkọ́, nítorí dúkìá ọwọ́ wọn ni: òmíràn a wọ ẹ̀wù ìlẹ̀kẹ̀, òmíràn a dé adé owó, òmíràn a máa fi ọ̀pá góòlù ti ilẹ̀, òmíràn a máa fi ṣíbí dáyámọ́ǹdì òkúta olówó iyebíye jẹun. Ẹ̀wù ẹlòmíràn dàbí fàdákà, kò sì sí èyí tí ó wọ bàtà tí a fi awọ ṣe. Bí eléyìí bá wọ bàtà góòlù, tọ̀hún a wọ ti idẹ, tìhín a wọ ìlẹ̀kẹ̀, àfi àwọn tí kò ní ẹsẹ̀ rárá ni wọn kò wọ nǹkan kan tí wọn ń tọ bí ọ̀pọ̀lọ́ kiri. Púpọ̀ nínú àwọn wọn-ọnnì ni ó dà bí ènìyàn gan-an bẹ́ẹ̀ ni ọba Igbó Olódùmarè pàápàá kò yàtọ̀ sí ìwọ àti èmi. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn mìíràn kò bá ènìyàn mu, àwọn wọ̀nyí sì ṣe fáàrí gẹ́gẹ́ bí ipò wọn. Ọsányìn ẹlẹ́sẹ̀-kan kò gbàgbé ẹsẹ̀ kan náà, nítorí ó wọ bàtá dáyámọ́ǹdì sí i. Àwọn ẹbọra kò jẹ́ fi àwo ẹlòmíràn jẹun. Olúkúlùkù ni ó mú àwo tirẹ̀ ti ilé wá, tí ó mú ṣíbí tí ó sì mú ife. Nígbà tí wọ́n máa padà àṣá álẹ́, wọ́n fi àwọn nǹkan iyebíye wọn-ọnnì ta bàbá mi lọ́rẹ. Ọ̀rọ̀ náà dùn nínú Igbó Olódùmarè, nítorí ẹbọra mu ọtí yó, wọ́n sì ń jó bí wọ́n ti lè jó mọ. Lẹ́hìn ìgbà tí olúkúlùkù lọ sí ilé rẹ̀ tán, bàbá mi kó àwọn ohun àlùmọ́nì tí wọ́n fi ta á lọ́rẹ jọ, eléyìínì sì mú kí ó di olówó fún ọjọ́ pipẹ́. Bí kò bá sí olè tí ó jà á nígbà tí òun kúrò nínú Igbó Olódùmarè tí ó wá si ilé ni, owó náà ìbá pọ̀ tó bẹ́l tí irú àwa wọ̀n yí kò bá tí ṣiṣẹ́ kí á tóó máa jẹun. Nítorí mo fẹ́ kí o rántí pé bàbá mi ti lọ sí ilé-ìwé kí ó tóó di pá ó bẹ̀rẹ̀ ọdẹ-ṣíṣe, ọgbọ́n tí ó sì kọ́ ní ilé-ìwé ń ràn án lọ́wọ́ àti kó owó jọ. Ìdílé ọ̀mọ̀wé kò sí ní ipò tálákà, bí wọn kò ní owó ni òní, wọ́n ‘b bọ̀ wáá ní lọ́la. Lẹ́hìn eléyìí pàápàá, nígbà tí bàbá mi ṣìnà sí inú Igbó Olódùmarè tí ó sí fi di pé ó pa Òjòlá-ìbínú tí í ṣe olórí ejò ayé gbogbo, bàbá mi tún rí àdó kan mú bọ̀ tí ó ń mú owó fún un. Ìwọ yóò máa gbọ́ nípa ìtàn eléyìínì níwájú. Báyìí ni ọba Igbó Olódùmarè náwó fún bàbá mi lajọ́ ìgbéyàwó yìí kò sì tí ì sí irú rẹ̀ ní ibẹ̀ láti ọjọ́ tí ọba náà ti gún orí oyè. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bàbá mi jí ní kùtùkùtù ó lọ dúpẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà tí ó rí ọba, ó dọ̀bálẹ̀ gbalaja, ó ní, Kábíyèsí, ki Ọlọ́run bùn yín lẹ́mìí, kí Èdùmàrè jẹ́ kí ẹ pẹ́ ní orí ilẹ̀ ayé. Ikú kò ní pa yín, àrùn kò ní gbé yín dè, ẹ óò gbó ẹ óò tọ́, ẹ ó ṣe baba wa pẹ́ títí. Ẹ kú ináwó mi àná, ẹ kú aájò, ẹ kú ìtọ́jú wa. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ohun gbogbo tí ẹ ṣe wọn-ọnnì, èmi kọ́ ni ẹ ṣe é fún, ẹ ṣe fún Ọlọ́run Ọba. Ó dá mi lóju’pé bí òṣìkà ti ń bọ̀ wáá kèrè ìkà, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni rere ń bọ̀ wáá jèrè ohun rere. Mo mọ nǹkan tí ẹ ṣe fún mi, èrè yín sì ń bẹ ní ọwọ́ Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, àǹfààní yín ń bọ̀ láti ọ̀run alákeji. Ojò ìbùkùn ṣú dẹ̀dẹ̀, yóó sì rọ̀ lé orí yín. Kábíyèsí, ẹ kíyèsí àwọn kòkòrò tí í máa jẹ ohun ọ̀gbìn wọn-ọnnì, bì wọ́n ti ń ba iṣu jẹ́, tí wọ́n ń ba ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ́, tí wọn kò sì jẹ́ kí àgbàdo yọ ọmọ, òwe ni Olódùmarè ń pa fún wa nì, nítorí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn aláìmoore ri, kòkòrò búburú ni wọ́n, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ọmọnìkejì wọn ní gbòǹgbò, kí onítọ̀hún máa baà lè dàgbà sóké, kí òun baà dúró sí ojú kan bi adágún omi. Ẹni tí a ṣe lóore tí kò mọ̀ ọ́n dàbí ẹni tí a gbà kúrò lọ́wọ́ ìjàǹbá tí ó rí àrẹ̀mọkùnrin ẹni tí ó tún yin ìbọn sí i, ìdájọ́ eléyìínì kò sí lọ́wọ́ ènìyàn, ó wà lọ́wọ́ Ọlọ́run Ọba. Kábíyèsí, mo mọ oore tí ẹ ṣe fún mi, ki Olódùmarè jẹ́ kí n lè fi hàn yín nípa ìwà mi pé ipò pàtàkì ni ẹ wà ní góńgó orí ọkàn mi. Báyìí ni bàbá mi sọ, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ olóore, inú onítọ̀hún sì dún wí pé òun kò ṣe oore fún aláìmoore, òun kò fi ẹ̀wù sányán bọ ẹlẹ́dẹ́ lọ́rùn, òun kò wọ ṣòkòtò fún ìnàkí, òun kò sán ìbàntẹ́ mọ́ obìnrin ni ìbàdi, òun kò fi àgàbàgebè ṣe olórí ẹgbẹ́, òun kò fi ọ̀bàyéjẹ́ ṣe alága nínú ìpàdé; òun kò ṣe ìtọ́jú ẹni tí kò yẹ. Ọba náà dáhùn ó sì wí pé: Olówó-ayé, o ṣeun púpọ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ. Irú nǹkan báyìí náà ni a wí pé kí àwọn ọmọ aráyé máa ṣe, ní dúdú, ni funfun, ni èyí tí kò dúdú tí kò funfun wí pé, kí ọmọdé fi ipò àgbà fún àgbà, kí àgbà náà fi ipò ọmọdé fún ọmọdé; kkí ìránńṣẹ́ fi ipò ọ̀gá fún ọ̀gá, kí ọ̀gá náà sì fi ipò ìrànńṣẹ́ fún iránńṣẹ́, kí ọkọ fi ipò aya fún aya, kí aya nàá sì fi ipò ọkọ fún ọkọ. Ìdí ọ̀rọ̀ mi rèé: ìwọ olówó-ayé, o dìde ni kùtùkùtù, nínú òtútù yìí, ó wá sí ilé mi, o jókòó, o bẹ̀rẹ̀ si yẹ́ mi sí, o kò wò mi bi ẹrú, o kò wò mí bí ìwọ̀fà, o kò wí pé kí ni arúgbó kùjọ̀ù yìí máa ṣe: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, o bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ rere nípa mi: o ṣe é púpọ̀; ẹni tì ó máa moore ni ọ́. Ṣebí ẹlòmíràn ni a ṣe èyí tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ fún, tí ó rí ni ní ọjọ́ kejì tí kò wo ni ní pìnṣín imú, tí a béèrè pé, O kò tilẹ̀ kí wa ni? Tí ó dáhùn tí ó wí pé, Mo jẹ ọ́ ní gbèsè ni? – Nítorí náà mo fẹ́ kí o mọ̀ pé kékeré ni èyí tí mo ṣe fún ọ lánàá, kí Olódùmarè dá ẹ̀mí sí, kí Ọlọ̀run jẹ́ kí á lè mọ ara wa pẹ́, nítorí bí ẹ̀mí bá wà, ìyókù kéré, ẹ̀mí làjùlọ. Ṣùgbọ́n mo f��́ẹ́ sọ kin ní kan fún ọ - ibànújẹ́ ti pọ̀ jù láàárin àwọn ọmọ ènìyàn tó bẹ́ẹ̀ ti àwa tí a jẹ́ ẹbọra kì í fẹ́ẹ́ gbé ààrin wọn. Bí kò bá jẹ́ pá àwọn ọmọ aráyé ń fi ara da ibànújẹ́ ni, ojoojúmọ́ nì wọn ìbá máa pa ara weọn. Olódùmarè fẹ́ràn ènìyàn ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn a máa fi ìwà wọn pín ara wọn ní ìyà sí Ọlọ́run Ọba, bẹ́ẹ̀ ni ẹlẹ́ṣẹ̀ kì í lọ ní ájìyà, ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará ayé kò jẹ́ ki ayé dùn mọ́ wọn. Èrò mi ni èyí, Olówó-ayé, jókòó sí inú Igbó Olódùmarè níhìn-ín nínú ààfin mi ki a máa gbádun ara wa. Bi ọdẹ bá ń wù ọ́ ṣe, gbé ìbọn kí o lọ máa ṣe ọdẹ nínu’igbó kí o sì máa padà wáá sùn ni ààfin. Ó wù mí kí o ro ọ̀rọ̀ yìí wò, nítorí kò yẹ kí ọmọdé kọ ìmọ̀ràn àgbàlagbà àfi bí ìmọ̀ràn náà bá jẹ́ èyí tí ó lè mú ìṣìnà bá ni. Lẹ́ẹ̀kan sí i mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún wíwá tí o wá, bá mi kí ìyàwó rẹ kí o sì kí ẹ̀gbọ́n ọmọ náà fún mi. Báyìí ni ọba náà sọ fún bàbá mi, bàbá mi náà sì dúpẹ́ bí ó ti yẹ kí ó ṣe, ó tún ṣe ìlérí pẹ̀lú pé òun yóó lọ si ilé kí òun fi ìmọ̀ràn náà síwájú ìyàwó òun, ìgbà tí àwọn bá jọ rò ó tán òun yóò wáá mú èsì fún ọba, lẹ́hìn èyí, wọ́n kí ara wọn ọba wọ inú iyẹ̀wù, bàbá mi náà sì bọ́ sí ẹ̀hìn òde. Nígbà tí bàbá mi dé ilé; ó wí fún ìyàwó rẹ̀, nígbà tí àwọn méjéèjì sì rò ó wò, wọ̀n pinnu pé àwọn óò dúró fún ìgbà pípé ní ọ̀dọ̀ ọba náà àti pẹ̀lú pé bí ó bá ṣeé ṣe àwọn lè kúkú fi ibẹ̀ ṣe ibùgbé àwọn. Báyìí ní apá kan tí ó ṣe pàtàkì ní ìgbésí-ayé bàbá mi parí. Apá kejì dùn púpọ̀ pẹ̀lú, ṣùgbọ́n , ọ̀rẹ́ mi, jẹ́ kí á fi èyìínì di òwúrọ̀ ọ̀la. Apá kejì yìí kò ní ṣòro fún ọ láti kọ nítorí bàbá mi pàápàá ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ èyìínì sílẹ̀, kí ó tóó kú, ìwé tí ó kọ ọ́ si kò si lọ́wọ́ mi nísisìyí, ó wà ní ilé, ìgbà tí mo bá sì mú un dé ni òwúrọ̀ ọ̀la, n ó fi ara mi sí ipò bàbá mi n ó máa kà á fún ọ, ìwọ yóó sì máa kọ ohun tí mo bá ń sọ sílẹ̀ bí ẹni pé bàbá mi ni ó tọ̀ ọ́ wá sí ilé tí ó ń sọ ìtàn ìgbésí-ayé ara rẹ̀ fún ọ. Ó dígbà o, máa retí mi ni àfẹ́mọ́júmọ́ ọ̀la. Báyìí ni ọkùnrin náà sọ tí ó lọ ni ọjọ́ náà: bẹ́ẹ̀ ni ọmọlúwàbí ni, kì í tàsé ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí èyí, bí ilẹ̀ ti ń mọ́ hàì ni ọjọ́ kejì ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí múra, mo sì ti gbé ohun ìkọ̀wé gbogbo sílẹ̀ kí ó tóó wọlé. ỌDẸ APERIN ṢÌNÀ SÍNÚ IGBÓ OLÓDÙMARÈ: GỌNGỌ SỌ Nígbà tí ó wọlé mi ní ọjọ́ kejì ó mú ìwé tí bàbá rẹ̀ fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ hàn mí; nínú ìwé yìi’, bàbá rẹ̀ sọ ìtàn ara rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti wà ni ọ̀dọ̀ ọba Igbó Olódùmarè ó sì dọ ọ́ títí dé ibi tí ó ti padà wá sí ilé. Ìgbà tí Àkàrà-oògùn ti fi eléyìí hàn mí tán ni ó jókòó rẹ̀gẹ̀jì lórí àga, ó ní kí n ka òun sí bí ẹni pé Olówó-yé mi òun, ó sì fi ara rẹ̀ si ipò bàbá rẹ̀ o ń ka ìwé náà fún mi, èmi náà mú ohun ìkọ̀wé mi, mo jókòó bí ó ti yẹ kí ẹni tí ń kọ̀wé jókòó, mo ń ba iṣẹ́ lọ. Ọ̀rọ̀ ti Olówó-ayé kọ sí inú ìwé ti ọmọ rẹ̀ kà fún mi ni yóò jẹ́ apá kejì ìwé yìí, ọ̀rọ̀ rẹ̀ náà ni ìwọ̀nyí: Èmi, Olówó-ayé, ọmọ Akọ̀wédìran, arẹwà lọ́kùnrin, mo wá sí Igbó Olódùmarè láti ṣe ọdẹ, mo bá ìṣòro pàdé lójú ọ̀nà, ṣùgbọ́n Olódùmarè yọ mí nínú wọn, ní ìgbẹ̀hìn mo dé ọdọ ọba Igbó Olódùmarè, ọba náà ni ó ṣe ìnáwó ìgbéyàwó fún mi, ìgbéyàwó ìyàwó mi tí ó bí ọmọ mi, Àkàrà-oògùn. Ọba náà ná owó púpọ̀ nítorí ìgbéwàyó mi yìí, ó ná owó, ó ná ara, ó ṣe ìtọ́jú mi bi ó ti yẹ kí ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹni ṣe nítorí náà mo sì rò pé ó yẹ kí n bẹ̀rẹ̀ sí máa kọ ìtàn ìgbésí-ayé mi yìí sílẹ̀ nítorí ojú mi ti rí nǹkan sí ẹ̀hìn, ìwà tí ọba yìí hù sì ti fi hàn mí pé nǹkan tí ojú ń rí nínú ayé yẹ ní kíkọ sílẹ̀ fún àwọn tí ń bọ̀ lẹ́hìn, nítorí ayé kún fún kòtò, pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti àwọn òkè gbogbo. Èmi tí mo bá Àǹjànnú-ìbẹ̀rù tí í ṣe oníbodè Igbó Olódùmarè jà tí ó sì dàbí ẹni pé tèmi parí láyé, mo tún bá ara mi nínú kẹ̀kẹ́ lẹ́hìn náà pẹ̀lú ìyàwó mi àfẹ́sọ́nà, mo tún di ẹni tí n gbé ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, mo di ẹni tí ń gbé ìyàwó tí ayé ń gbọ́ tí ọ̀run ń mọ̀; n ó kọ ìtàn ìyókù ìgbésí-ayé mi sílẹ̀ nítorí n kò mọ ohun tí ń bọ̀ níwájú. Olódùmarè ni o ń kọ́ ọba Igbó Olódùmarè ní ọgbọ́n, kò jẹ́ hùwà bí aláìgbọ́n kí ó máa wá ohun ìkọ̀sẹ̀ sí àlejò lẹ́sẹ̀ nítorí òun ti mọ eléyìí wí pé ìlá tí kò fẹ́ràn àlejò ń ṣe ara rẹ̀ ní ìjàǹbá, ó sì rọrùn fún ọmọ ọlọ́dúnmẹ́ta kí ó ṣe alága ìgbìmọ̀ ìlù ju kí ìlú tí ó kórìíra àlejò ní ìlọsíwájú. N kò sì gbàgbé ààfin náà láéláé, ọba Igbó Olódùmarè ṣe ìtọ́jú mi. Nígbà tí ó di oṣù kẹfà tí mo ti ń ggbé à[fin ọba yìí, oyún ìyàwó mi di oyún oṣù kẹta, nígbà tí wọ́n lóyún ọmọ mi àkọ́bí, Àkàrà-òògùn, mo múra láwùúrọ̀ ọjọ́ kan báyìí, mo lọ sí igbó lọ ṣe ọdẹ ní àkókò yìí, mo ti di ọdẹ aperin. Ìyàwó mi sìn mí sí ọ̀nà, nígbà tí ó sì máa padà, ó wí fún mi kí n gbìyànjú tètè dé nítorí kí ojú má baà ro òun. Lẹ́hìn èyí, ó súre fún mi pé n óò rí ẹran pa ó sì tún wí fún mi pé bí mo bá rí ẹyẹ àparò kí n pá ọ̀kan bọ̀, nítorí ẹyẹ àparò ń wu òun láti jẹ, ṣé bí àwọn obìnrin obìnrin bá ti lóyún àyípadà pàtàkì ti dé sí wọn, kì í ṣe gbogbo oúnjẹ ni ó máa ń wú wọ́n jẹ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí kò bá ṣe ìtọ́jú aboyún kúrò ni ipò ènìyàn, òun ni à bá máa pè ní paramọ́lẹ̀ tí ó gbe àwọ̀ ekòló borta: eejò olóró ni paramọ́lẹ̀ ṣùgbọ́n jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni ekòló ń siré tirẹ̀ kiri. Nítorí náà mo ń tọ́jú ìyàwó mi púpọ̀ púpọ̀ ní àkókò yìí, mo ń kẹ́ ẹ gan-an ni, nígbà tí ó sì sọ̀rọ̀ ẹyẹ àparò mo pinnu àti wá àparò dé góńgó. Àti pàápàá nígbà tí ata pẹ̀lú àlùbọ́sà bá ṣe ìpàdé lórí àparò, nǹkan náà yóò bọ́ sí i. Lẹ́hìn tí ìyàwó mí sìn mí sí ọ̀nà díẹ̀ mo kí i mo wí pé: ‘Máa padà lọ sí ilé, ìyàwó mi, àpé, máa wo ilé dè mí o, èmi náà kò ní pẹ́, ìrẹsì ni kì o sè dè mí, nítorí àkàṣù ẹ̀kọ ni mo jẹ lánàá, bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ ni ọkà ni mo jẹ ní ìjẹta; n ó gbìyànjú àti pa ẹran bọ̀, bí ọwọ́ bá sì ba àparò, a jẹ́ pé nǹkan náà yóó ṣe ẹnu re. Bí ẹnikẹ́ni bá wá mi dé ilé, wí fún olúwaarẹ̀ pé mo yára bọ́ sí ẹ̀hìn odi.’ N kò rìn jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà tí mo dé apá kan nínú Igbó Olódùmarè tí ó yà mí lẹ́nu gidigidi, nítorí níbẹ̀ ni àwọn igi kò ti ní gbòǹgbò ṣùgbọ́n síbẹ̀ ti wọ́n dúró ṣanṣan tí ewé wọ́n sì dúdú mirinmirin. Àwọn ẹranko ibẹ̀ ń fọhùn ènìyàn bákan náà sì ni àwọn ẹyẹ. Nígbà tí mo dé inú igbó yìí n kò rí nǹkankan rárá, n kò rí ẹranko bẹ́ẹ̀ n kò sì rí ẹyẹ, ọ̀kẹ́rẹ́ kò tilẹ̀ gun igi kọjá lójú mi. Mo rìn títí n kò rí nǹkan kan. Nígbà tí ó ṣe, atẹ́gùn bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́, gbogbo àwọn iggi tí kò ní gbòǹgbò wọn-ọnnì sì ń fi orí balẹ̀ wọ́n tún ń dìde. Atẹ́gùn náà pọ̀ gidigidi ó fẹ́ síhìn-ín ó fẹ́ sọ́hùn-ún, àwọn igi àti ìtàkùn sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu ara wọn. Ọ̀ràn náà le gidigidi, bí kò sí àánú Ẹlẹ́dàá mi ni, igi ìbá ti dá pa mí - Ọlọ́rùn tóbi lọ́ba. Nígbà tí ó oẹ́díẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn igi gíga wọn-ọnnì forìbalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀dọ̀ mi mo yára jókòó sí orí rẹ̀ kì ó tóó dìde, ìgbà tì atẹ́gùn sì tún fẹ́ tí ó dìde tán tèmi ti igi náà ni a dìde. Bẹ́ẹ̀ ni igi náà ga, bí ènìyàn bá ń wò mí ní ìsàlẹ̀ n kò ju kékeré lọ. Inú mi kọ́ dùn nígbà tí mo dé òkè lọ́hùn-ún nítorí mo rí gbogbo àgbègbè ibẹ̀ kedere, ewéko gbogbo dúdú mirinmirin, àyíká náà sì lẹ́wà gidigidi. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó pẹ́ dípò ayọ̀ ẹkún ló yẹ kí n máa sun. Níto’ri nígbà tí mo dé òkè tán atẹ́gùn kò fẹ́ mọ́, ìtàkùn dúró bí ó ti wà rí, àwọn igi kò sì fi orí balẹ̀, ṣé èmi ìbá mọ̀ kí n tètè bẹ́ sílẹ̀ bí atẹ́gùn bá fẹ́ ṣùgbọ́n nígbà tí igi ti wà ní ìdúró, àti sọ̀ kalẹ̀ kò lè ṣàìjẹ̀ ìṣòro fún mi. Nítorí n kò lè bẹ́ láti orí òkè gíga sí ilẹ̀, bí mo bá ṣe èyínì àti apá àti ẹsẹ̀ mi ni yóò yún wómúwómú. Bẹ́ẹ̀ ni igi náà ga tó bẹ́ẹ̀ ara rẹ̀ sì dán tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹni tí ó lè sọ̀kalẹ̀ fún ara rẹ̀ rárá. Eléyìí mú ìrònú bá mi mo sì bẹ̀rẹ̀ sí kábàámọ̀ ara tí ó ré mi tí mo fi hu irú ìwà òmùgọ̀ bẹ́l. Ibi tí mo tí ń ronú yìí ni mo ti rí àgbọ̀nrín kan tí ó ń kọjá lọ mo sì ké sí i mo ní, Àgbọ̀nrín ò, jọ̀wọ́ yọ mí nínú ìhámọ́ yìí o. Igi ló ṣubú lulẹ̀ tí mo jókòó lé orí igi àfi ìgbà tí atẹ́gùn fẹ́ tí igi tí ó ṣubú lulẹ̀ dìde, ìdì rẹ̀ náà sì ni eléyìí tí ìwọ fi rí mi tí mo lé téńté lórí igi. Olódùmarè kò ní jẹ́, kí o wọ ẹ̀wọ̀n lọ́sàn-án gangan. Ọlọ́jọ́-òní kò ni jẹ́ kí ebi ẹnu pa ọ́ o; àgbọ̀nrín mi ọ̀wọ́n pàtàkì ni ìwọ jẹ́ láàrin àwọn ẹranko, nítorí ìwọ funfun ìwọ sì pupa bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ rẹ lágbára ìwọ si ní ìwo lórí ṣaraṣara. Àgbẹ̀ tí kò bu ọlá fún ọ kò lèrí iṣu jẹ, olóko tí ó bá wí pé kí ni ìwọ jámọ́ yóó maa ṣiṣẹ́ dànù ni, nítorí náà mo bẹ̀ ọ́ nítorí Ọlọ́run Ọba má ṣàì gbìyànjú àti yọ nínú ọ̀ràn mi yìí kí n kúrò níbi tí mo bọ́ há sí lórí igi. Bí o bá yọ mí n kò ní í gbàgbé rẹ láéláé èmi yóò mú ọ lọ sí oko àgbẹ̀ kan tí ilá pọ̀ sí, ìwọ yóó sì jẹun ikùn rẹ yóó yọ bọ̀ǹbọ̀.’ Nígbà tí mo wí báyìí tán àgbọ̀nrín náà dá mi lóhùn ṣùgbọ́n ìdáhùn rẹ̀ lòdì sí ìrètí mi. Ó wí báyìí pé: ‘Ìwọ ẹni tí ń bẹ lórí igi, àánú rẹ ṣe mí jọjọ; ṣùgbọ́n kò sí nǹkan tí mo lè ṣe fún ọ. Àwa àgbọ̀nrín kì í gun igi nítorí àwa yàtọ́ sí ejò àti ọ̀kẹ́rẹ́, bẹ́ẹ̀ni àwa kò bá ọ̀bọ àti ìjímère mu. Ìbá jẹ́ pé mo lè gún òkè ni, èmi ìbá lọ ní ti eléyìí ná kí n tóó padà wáá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ. Bí ìwọ ti rí mi lónìí, iṣẹ́ ni àwọn ẹranko rán mi, nítorí òní ni ọjọ́ ìpàdé wọn. Ibi kékeré ni nǹkan ti í lọ, ẹni tí a rán ní iṣẹ́ tí ó ń ṣiré lójú ọ̀nà, aláfojúdi ẹ̀dá ni; ẹni tí a fún ní nǹkan kékeré tí kò dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni, aláìmoore ni, nítorí náà mo ń fẹ́ẹ́ lọ, ojú ń kán mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ rẹ jọ bí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ìwọ sì ṣe ìlérí àti fi oko ìla hàn mí, síbẹ̀ n kò ní i lè dúró fún ọ ní ímọ̀ràn kan. Kò sí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nínú Igbó Olódùmarè, nítorí wíwọ́ ni ọ̀nà àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n ọ̀nà òótọ́ gbòòrò ó ń dán kooro – ó dígbà o.’ Kò pẹ́ púpọ̀ tí àgbọ̀nrin lọ tán tí mo rí ehoro ti ń kọjá lọ mo sì tún gbìyànjú mo ké sí i mo ní, ‘Ehoro ò! Òun náà sì dá mi lóhùn, ó ní, Ìwọ ta ní ń pè mí lórí igi? Mo sì tún dáhùn mo ní, Èni ọmọ ènìyàn ní ń pè ọ́ lórí igi, mo fẹ́ kí o ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi kí n lè tètè kúrò níbi tí mo lé téńté sí lórí igi. Ẹ̀fúùfù ló fẹ́ tí igi ṣubú lulẹ̀ tí mo jókòó, àfi ìgbà tí ẹ̀fúùfù kò fẹ́ mọ́ tí igi dìde mọ́ mi ní ìdí tí mo sì bá igi lọ sí òkè tí àti padà di ìṣòro fún mi. Ṣùgbọ́n bí mo ti rí ọ nísisìyí, ọkàn mi balẹ̀, nítorí ta ni ẹranko náà nínú igbó tí yóò wí pé òun kò mọ ìwọ, ọ̀gbẹ́ni ehoro? Ìwọ kò dà bí àwọn ẹlòmíràn tí ojú-inú wọ́n ti fọ́, nítorí bí ojú inú bá ti fọ́ bi olúwaarẹ̀ tilẹ̀ ń ṣe ibi kò ní i ríran rí i pé ibi ni òun ń ṣe. Bí ìwọ bá rí ẹni tí kò ní ìtìjú, mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ojú-inú eléyìínì ti fọ́. Ṣùgbọ́n, ìwọ lágbára nínú àwọn ẹranko, ìwọ lè sáré ju púpọ̀ nínú wọn, etí rẹ kò sì kéré bí a bá fi wé bí ìwọ pàápàá ti tóbi mọ. Nítorí náà, jọ̀wọ́ má ṣàìràn mi lọ́wọ́ nítorí ọ̀ràn yìí kí o sì gbà mí ní ìyànjú ọ̀nà tí n ó gbà tí n ó fi sọ̀klẹ̀ kúrò tí mo dúró sí téńté.’ Báyìí ni mo sọ̀rọ̀ dídùn ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ èsì ehoro tún lòdì sí ìrètí mi. Ó dáhùn ó sì wí pé: Ọ̀rọ̀ tí o sọ rọ̀ bí ọ̀gẹ̀dẹ̀ pupa kò fẹ́ èsì tí ó le bí òkúta dídán inú omi. Ọ̀rọ̀ rẹ wù mí, ìwọ ọkùnrin yìí, bí kò bá sí ṣe iṣẹ́ tí wọ́n rán mi ni, èmi ìbá dúró tì ọ́ níhìn-ín, èmi ìbá sì sa ipá dé góńgó, èmi ìbá rí i pé ìwọ sọ̀kalẹ̀ níbi tí ìwọ dúró téńté sí lórí igi. Ṣùgbọ́n máṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí bà ọ́ lọ́kàn jẹ́, nítorí àwọn ẹlòmíràn ń bọ̀ lẹ́hìn mi, bẹ́ẹ̀ ni bí ìwọ kò bá fi ọ̀rọ̀ rẹ jáfara tí ìwọ ń wí fún àwọn ẹni tí ń kọjá, nǹkan náà kò ní pẹ́ bọ́ sí i. Ṣùgbọ́n mo bẹ̀ ọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, máṣe dà bí àwọn aláìmóye ènìyàn, tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara wọn tí wọn kì í fi ọ̀rọ̀ wọn lọ ènìyàn, àwọn wọn-ọnnì a fi aṣọ bo ìwèrèpè mọ́ra, ọ̀rọ̀ burúkú a fi ara mọ́ wọn tímọ́-tímọ́, nígbà ti wọn bá sì ń rẹ́rìn-ín lójú àwọn ọmọ aráyé báyìí, ìbànújẹ́ a fẹ̀hìn tí lórí àga ní ibi kọ́lọ́fín inú wọn. ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n máa lọ ní tèmi, nítorí òní ni ìgbìmọ̀ àwọn ẹranko, àwọn àgbàlagba ni wọ́n rán mi ní iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá ń fẹ́ kí òun dàgbà, olúwaarẹ̀ kò ní í fi nǹkan àgbà jáfara – pẹ̀lẹ́ o, ọdẹ aperin, ó kú làásìgbà náà, ó dìgbà díẹ̀ ná, kí orí rẹ má ṣàìgbé ọ kalẹ̀ ní ibni tí ìwà òmùgọ̀ gbé ọ lé téńté.’ Nígbà tí ehoro pári ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó ki iré mọ́lẹ̀, ó sáré tagbáratagbára: ò ku èmi nìkan sí orí igi, ètè mi gbẹ, itọ́ ẹnu mi yí, ikùn mi rí pẹlẹbẹ, ojú mi rí kan-ǹ-do, mo lé góńgó lórí igi, mo dà bí ìjìmèrè, mo fi ara wé ìnàkí, mo rántí ilé, mo rántí ọ̀rẹ́, àárò sọ mi, ìyà, ẹgbẹ̀ta jẹ mí, -àbùkù ẹgbẹ̀rin tọ lé mi, mo pa òṣé ńlá, mo sọkún àgbàlagbà, mo fa ojú ro, mo wo òkè, mo wo ìsàlẹ̀, mo rónú títí, bẹ́ẹ̀ ni n kò ri nǹkan ṣe nǹkan. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́hìn èyí tí àkúté kan ń rékọjá, ìrọ́jú ni mo sì fi mọ̀ pé èkúté ni, nítorí ibi tí mo wà jìnnà si ìsàlẹ̀, ohun gbogbo sì kéré gidigidi. Mo ké sí i, mo ní Èkúté ò! Òun náà sì dáhùn, ó ní, Ta ní ń pe èmi èkúté, èmi èrò inú igbó, èmi èrò inú aginjù, èmi tí mò ń bá ayé mi kiri láàárin ìtàkùn àti igi? Èmi náà sì fèsì mo wí pé: Èmi Olówó-ayé ni mo ń pè ọ́, Èmi ọmọ Akọ̀wédìran, èmi ọdẹ aperin, ọkọ Àjẹ́dìran, ẹni tí ó wáá ṣe ọdẹ nínú igbó, tí ìwọ bá téńté lórí igi. Jọ̀wọ́ ràn mi lọ́wọ́ èkúté ti ń ṣiré kiri; kò sí ẹni tí ó kéré níwájú Ọlọ́run Ọba àfi alábòsí ènìyàn tí ó pe o olè ki ó wáá jà tí ó lọ tún lọ wí fún olókko kí ó wáá ṣọ́ oko, olóko dúpẹ́ olè dúpẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìdájọ́ alábòsí di ọ̀run alákeji. Ìwọ èkúté Igbó Olódùmarè, ìwọ kéré lójú ènìyàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ tóbi ju òkété ibòmíràn lọ, ṣùgbọ́n kinní kan ni mo fẹ́ kí o mọ̀: ìwọ kò kéré níwájú Ọlọ́run Ọba. Ìwọ kì í ṣe àgàbà gebè tí ó fi ẹ̀jẹ̀ sí inú tí ó tu ita funfun jáde, tí ó yin ènìyàn lójú tí ó bú ènìyàn lẹ́hìn, èkúté mi ọ̀wọ́n, jẹ́ kí n sọ ìtàn kékeré kan fún ọ - lẹ́jẹ́ kan, èmi àti alábòsí jọ wà nínú ẹgbẹ́, nígbà tí ó ṣe àkíyèsí pé ọkùnrin kan ń fẹ́ẹ́ ba ẹgbẹ́ jẹ́, gbogbo wa pa ẹnu pọ̀ pé kí ọkùnrin náà kúrò nínú ẹgbẹ́, àfi ìgbà tí a túká ní ibi ìpàdé tán tí alábòsí rọra yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tọ ọkùnrin náà lọ tí ó wí fún un pé òun kò ni ọwọ́ nínú èrò wa. Àsẹ̀hìnwá-àsẹ̀hìnbọ̀ gbogbo ẹgbẹ́ gbọ́, ojú sì ti alábòsí gidigidi, nígbà tí a béèrè ọ̀rọ̀ yìí, alábòsí dáhùn bí akólòló ó dàbí ẹni pé kí gbogbo wa bẹ́ ẹ lórí. Èkúté mi ọ̀wọ́n, ìwọ kò ddàbí àwọn wọ̀nyí; mo sì bẹ̀ ọ́ kí o má ṣàì fi ìwà òdodo rẹ hàn mi lónìí, kí o má ṣàì fi òótọ́-inú bá mi lò, kí o wí fún mi nísisìyí pàtó, ọ̀nà tí mo lè gbà fi yọ kúrò nínú ìhámọ́ yìí, níbi tí ìwà òmùgọ̀ gbé mi lé téńté.’bẹ́ẹ̀ ni mo sọ̀rọ̀ fún èkúté yìí òun náà sì fún mi ní èsì tí ó yẹ, ó dáhùn ó wí pé: Ìwọ ọdẹ tíń bẹ lórí igi, mo dúpẹ́ púpọ̀ fún ọ̀rọ̀ rere tí o sọ nípa mi. Rọ́jú mú sùúrù díẹ̀ sí i. Sùúrù ni àwọn olórí mú kí wọ́n tóó dé ipò oórí, sùúrù ni àwọn aṣáájú mú tí wọn kó fi kò àwọn èrò ẹ̀hìn ṣìnà, sùúrù ni Ọlọ́run Ọba mú tí kò fi run àwọn ọmọ aráyé ṣuṣu. Òní ni ọjọ́ àwùjọ àwọn ẹranko, níbi tí onírúurú ẹranko gbogbo péjọ sí tí wọ́n ń péré nípa ìgbésí-ayé wọn, ebi ní ń pa mi tí mo rọra yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ láàárin wọn, nítorí bí ebi bá ti kúrò nínú iṣẹ́, iṣẹ́ bùṣe. Ṣùgbọ́n kíyè sí ọ̀rọ̀ tí mo máa bá ọ sọ nítorí ki ìwọ ba lè tètè yọ, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ni ó ti hu irú ìwà tí ìwọ hù yìí rí, ṣùgbọ́n o;lúkúlùkù wọn ló kú sí orí igi. Nígbà tí ìpàdè bá parí, ìwọ yóò gbó agogo, lẹ́hìn agogo ni ìwọ yóó maa rí ẹ̀fúùfù líle, ẹ̀fúùfù náà yóò lágbára ju èyí tí ó kọ́ fẹ́ lọ. Àkókò náà ni kí ìwọ wá ọ̀nà kí ìw\\o lè jáde. Ṣùgbọ́n ẹ̀fúùfù náà yóò lágbára gidigidi, nítorí bí àwọn igi ti ń fi orí balẹ̀ náà ni wọn óò tún máa dìde. Jọ̀wọ́ ṣọ́ra kí igi má baà gbá ọ lórí, kí igi má baà lù ọ́ ní ìpàkọ́, kí egungun orí rẹ má baà fọ́, ki ìmùdùnmúdùn orí rẹ má baà jáde, kí ìwọ má baà ṣe bẹ́l di èrò ọ̀run. Ọ̀rọ̀ tí mo ní í sọ kò ní í ju eléyìí, mò ń wá óunjẹ lọ nísisìyí, nígbà tí mo bá jẹun tán n óò tún padà wáá wò ọ́; ó dígbà o, o kú rògbòdìyàn náà, ki Ẹlẹ́dàá rẹ má ṣàì gbé ọ sọ̀kalẹ̀ níbi tí ìwọ lé téńté sí lórí igi.’ Báyìí ni èkúté sọ fún mi mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ gidigidi, mo ní, Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ o, ìwọ èkúté, ki Ọlọ́run bò ọ́ ni àṣírí, kí Olódùmarè dà ọmọ sí fún ọ; èdè rẹ yé mi dáradará, mo gbọ́, n ó máa retí agogo náà, n ó si múra sílẹ̀ de èfúùfù, n kò sì ní í jẹ́ kí igi dé ibi ìpàkọ́ mi. Kí ìwọ, náà máa kíyè sára o, jẹ́ẹ́jẹ́ ni kí o máa rìn lọ; ọmọ onílẹ̀ tẹ̀ ẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, àjèjì tẹ̀ ẹ́ gìrìgìrì, má ṣe jẹ́ kí pàkúté mú ọ o. Nítorí bí pàkúté bá lọ bá ọ ní ibiburúkú kò ní í dára, bí ó bábá orí, orí lè fọ́, bí ó bá bá ẹsẹ̀, ẹsẹ̀ lè gé dànù, òuun sìlè sọ olúwaarẹ̀ di ẹni tí ń rìn yẹ́ńkúyẹ́ńkú kiri. Pẹ̀lẹ́ o, èkúté, bá mi kí àwọn ará ilé rẹ; nìgbà tí mo bá sọ̀kalẹ̀ tán, n ó wáá mọ ihò rẹ, ṣùgbọ́n bí n kò bá sì lè sọ̀kalẹ̀ mọ́, a jẹ́ pé a lè ṣàìtáun rí ara wa mọ́ o.’ Nígbà tí mo parí ọ̀rọ̀ mi tán, èkúté mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó ń wá óunjẹ òòjọ́ rẹ̀ lọ, ó sì wáá ku èmi, mo lé téńté s’orí igi. Nígbà tí ó pẹ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ agogo, eléyìínì sì fi hàn mi pé àwọn ẹeranko parí ìpàdé wọn. Mo yára jókòó dáradára mo dì mọ́ ìtàkùn kan tí ó fà mọ́ igi tí mo wà lórí rẹ̀ mò ń retí ẹ̀fúùfù líle tí èkúté sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi. Àṣé ìtàkùn tí mo dì mọ́, ara igi mìíràn ló ti dìde; nígbà tí atẹ́gùn sì bẹ̀rẹ́ tí igi tí mo jókòó lé ń fẹ́ lọ foríbalẹ̀ igi tí ìtàkùn náà dì mọ́ dìde dúró ṣe ni mo sì bá ara mi tí mo ń fi dirodiro. Inú eléyìí ni mo wà títí igi tí mo dúró lé lẹ́ẹ̀kan fi foríbalẹ̀ tán ṣùgbọ́n mo ń retí ìgbà tí yóó tún dídé wáá bá mi. Nígbà tí ó dídé dé òkè tán, wéré mo mú ọwọ́ kúrò lára ìtàkùn tí ó lọ́ mọ́ igi mìíran yìí mo sì yára dì mọ́ igi tèmi. Lẹ́hìn èyí ni igi tèmi tún wáá lọ foríbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, bí orí rẹ̀ sì ti balẹ̀ báyìí, mo bẹ́l sílẹ̀ kí ó tóó tún dìde. Nígbà tí mo dé ilẹ̀ o rẹ̀ mi púpọ̀ nítorí mo ti pẹ́ púpọ̀ lórí òkè, ebi sì ti pa mí inú mi ti di pẹlẹbe, mo bà rọra jókòó sí apá kan mo ń simi. Kò pẹ́ púpọ̀ tí mo ń simi yìí mo bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ìró bọ̀ lẹ́hìn mi nígbà tí mo sì wo ibẹ̀ mo rí onírúurú ẹranko, wọ́n ń ti ìpàdé bọ̀ wọ́n sì kọjú sí apá ọ̀dọ̀ mi, ẹ̀rù bà mí gidigidi n kò sì tó ẹni tí ń yìnbọn si èyíkéyì nínú wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹranko alágbára ní ń bẹ nínú wọn. Mo yàra gbé ibọn mi mo bẹ̀rẹ̀ sí sálọ. Èyí tí ó wáá yà mí lẹ́nu ni èyí pé ibikíbi tí mo bá yà sí ni àwon ẹranko eọ̀nyí ń yà sí àfi bí ẹni pé èmi ni wọ́n ń wá kiri ni, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń lọ tiwọn ni, ṣe ló jọ bẹ́ẹ̀ lójú mi. Ibi tí mo ti ń sá kiri yìí ni mo ti rí abẹ̀ ìtàkùn ńlá kan tí ó kún fún ewé, tí ó ní oríṣiríṣi ìpàǹtí, tí ó dà bí awùsá tí ó si rí rẹ̀gẹ̀jìrẹ̀gẹ̀jì. Mo ki orí bọ́ inú ìpàǹtí yìí. Nígbà tí mo máa jáde, orí mi kún fún onírúurú ewé gbígbẹ, pẹ̀lú ẹ̀rún igi. Nígbà tí mo jáde tán, mo simi díẹ̀. Ibi tí mo tí ń simi yìí ní\i mo ti gbé ojú sókè tí mo rí àwọn ẹyẹ ńlá gbogbo ti wọ́n ń fò káà kiri mo sì pa ọ̀kan nínú wọn. Mo dá iná mo sun ọ̀kan náà mo sì jẹ ẹ́ tán pátápátá. Lẹ́hìn èyí mo lọ sí ibi omi kékeré kan báyìí tí ó ṣán la’ti orí àpáta kan wá sí ìsàlẹ̀ mo sì fi ewé títóbi bu omi mu. Nígbà tí mo simi díẹ̀ lẹ́hìn èyí mo wáá dìde mo ń wọ́ ọ̀nà tí n óò bá padà lọ sí ibùgbé mi lọ́dọ̀ ọba Igbó Olódùmarè ṣùgbọ́n n kò rí ọ̀nà rárá, mo rìn síwá mo rìn sẹ́hìn kò tilẹ sí ibi tí ó jọ bí ẹni pé mo mọ̀. Bí iré bí iré ilẹ̀ ń ṣú lọ síbẹ̀ n kò rí òye ọ̀nà rárá. Báyìí ni mo ṣe tí ilẹ̀ ṣú mi sí inú igbó náà lọ́jọ́ yìí. Kí n máa bá ọ̀rọ̀ lọ bi ilẹ̀ bí ẹní, mo fẹ́ kí gbogbo ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe tí mo ṣìnà sínú igbó náà odidi ọdùn mẹ́ta. Ní àkókò tí mo ṣìnà yìí, n kò lè fi ẹnu mi sọ fún àwọn ènìyàn, ó sì ṣòro fún ọwọ́ mi láti kọ fún àwọn aráyé, gbogbo àwọn nǹkan àjèjì àti nǹkan ìjìnlẹ̀ tí mo rí, tí mo gbọ́, tí mo bá lò, tí ó sì ṣe alábàápàdé mi. Lóòótọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ pàtàkì nínú tí kò rí ènìyàn láti sọ̀rọ̀ náà fún dàbí ẹni tí ebi ń pa tí ó rí oúnjẹ tí kò gbọdọ̀ jẹ, síbẹ̀ kì í ṣe ohun gbogbo tí àgbàlagbà bá rí ni àgbàlagbà lè sọ. N ó sọ ìba díẹ̀ ṣókí nínú ohun tí ojú mi rí nínú ọdún mẹ́ta yìí kí ó tóó di pè mo rí òye ọ̀ràn mi. Fún odidi ọdùn kan gbáko èèso igi ni mo fi ṣe pàtàkì oúnjẹ. Mo yìnbọn títí ẹ̀tù fi tán ni àpò mi ṣùgbọ́n àwọn ẹran tí mo rí pa ní àkókò tí ẹ̀tù wwà ṣe mí lóoore gan-an ni. Nígbà ti ẹ̀tù tán, mo bẹ̀rẹ̀ sí okùn-dídẹ sí ojú ọ̀nà àwọn ẹranko mo sì ń fi àdá mi pa ẹja káà kiri inú omí ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ mo ń yí inú igbó kiri mo sì ń wá èèso igi tí n ó jẹ. Inú ihò kan báyìí ni mo fi ṣe ilé; nígbà tí ó sì pẹ́ díẹ̀ tí mo ti ń gbé inú ihò náà mo tún un ṣe dáadáa mo sì ṣe onírúurú yàrá sí í. Mo ṣe ibùbùn lọ́tọ̀. Mo wá ewé wẹẹrẹ mo kó o jọ mo sì kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewé títóbí mo fi bo ogunlọ́gọ̀ ewé wọn-ọnnì, mo fi eléyìí ṣe ìrẹ̀rí sí ibùsùn mi. Mo wá òkúta ńlá kan mo fi ṣe ilẹ̀kún mo sì lu ihò kéékèèkéé sí òkè ihò náà, mo fi àwọn wọn-ọnnì ṣe fèrèsé, nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òkúta ni gbogbo ẹ̀gbẹ́ ihò mi yìí, síbẹ̀ apá kan orí rẹ̀ ni ó jẹ́ òkúta; apá kan tí ó sì jẹ́ erùpẹ̀ ni mo ṣe àwọn fèrèsé mi sí. Àwọn ẹranko ńlá gbogbo ni ó ti ń gbé inú ihó yìí kì n dé ṣùgbọ́n nígbà tí mo ti dé ibẹ̀ ni wọ́ọ́n ti sá jáde fún mi. Ibi tí mo ti ń yí igbó kiri mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìn, ìkarawun wọn ni mo sì fi ń pọn omi tí mo wọ́n jọ lẹ́sẹẹsẹ sí inú ihò mi. Báyìí ni mo ń ṣe tí mo ń lo ìba àǹfáàní díẹ̀ tí mo ní tí mo sì ń bá ìgbésí-ayé mi lọ. Nígbà tí ó di oṣù kẹjọ ti mo dé inú igbó yìí, ẹ̀fúùfù ńlá kan fẹ́ lọ́jọ́ kan báyìí; ẹ̀fúùfù náà pọ̀ púpọ̀, ojú àwọsánmọ̀ sí kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpàǹtí. Ibi tí mo ti ń wo òkè ni mo déédéé rí háhá àgbàdo kan tí ẹ̀fúùfù ń gbé kiri mo sì ń ṣe àkíyèsí ibi tí háhá àgbàdo náà yóó balẹ̀ si. Nígbà tí ó máa balẹ̀ ó balẹ̀ sí ojú odò kékeré kan tí ó ń sán, odò náà sì ń gbé e lọ. Mo yára tẹ̀lé e mo sì ń lé háhá náà lọ títí ó fi dé ibi ìtàkùn kan tí ó wà lójú omi tí ó dúró; níbẹ̀ náà ni mo sì bá a tí mo mú un. Ohun tí ó jẹ́ kí n tẹ̀lé e ni pé mo fẹ́ẹ́ wò ó dáadáa bóyá ibi tí ẹ̀fúùfù ti fẹ́ ẹ wá kò jìnnà, nípa bẹ́ẹ̀ mo sì lè rí àmì láti fi hàn mí pé síbẹ̀síbẹ̀ mo lè yọ nínú ìhámọ́ mi. Nígbà tí mo wo háhá náà n kò rí àmì kan ṣoṣo láti fi hàn mí pé ibi tí ó ti wá sún mọ́ mi rárá nítorí gbogbo àkíyèsí tí mo ṣe ni ó fihàn mi pé ọ̀nà ibi tí háhá àgbàdo náà ti wá jìnnà, nítorí ibi tí mo mọ̀ tí àgbàdo bẹ́ẹ̀ wà pàápàá jjìnnà ssí Igbó Olódùmarè gidigidi. Ṣùgbọ́n ohun ayọ̀ tí mo rí ni pé, nígbà tí mo wo inú háhá náà dáadáa mo rí ẹyọ àgbàdo gbígbẹ kan. Nígbà tí mo ronú títí ohun tí mo lè ṣe nípa ẹyọ àgbàdo yìí tí n kò rí, mo ní, ‘Jọ̀wọ́ Ọlọ́run má ṣàìkọ́ mi lọ́gbọ́n tí n ó gbà pẹ̀lú àgbàdo yìí o. Lẹ́hìn èyí mo mú háhá mi náà lọ sí inú ihò mi mo sì sùn mọ́jú ọjọ́ náà. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ṣe ni ó dàbí ẹni pé bí èmi ti sùn lọ nì ọkàn mi kò sùn, ó ń ronú lórí àgbàdo yìí, nítorí bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀lopọ̀ nǹkan tí ènìyàn bá ń ronú rẹ̀ máa ń déédéé dẹ olúwaarẹ̀ lọ́rùn àti ṣe bí olúwaarẹ̀ bá sun oorun díẹ̀ tí ọkàn simi. Bí mo ti jí ni ọkàn mi ti sọ fún mi pé kí n lọ ṣer oko kékeré kan kí n lọ gbin ẹyọ àgbàdo kan náà sí í. Bẹ́ẹ̀ ni mo múra tí mo ṣán oko tí mo gbin àgbàdo mi kan yìí sí i. Nígbà tí ó ṣe, àgbàdo yìí hù, bí iré ó dàgbà ó sì yọ ọmọ, ó yọ ọmọ méjì ńláńlá. Nígbà tí wọ́n gbó n kò jẹ wọ́n mo tọ́jú àwọn àgbàdo ńlá méjì náà títí wọ́n fi gbẹ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ló wà lára àgbàdo náà. Nígbà tí ó tún di àkókò òjò mo gbin gbogbo ẹyọ àgbàdo tí mo ní sí oko títóbi kan báyìí tí mo ṣe; nígbà tí àwọn àgbàdo mi si wáá gbó, mo bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá rí mi lákòókò yìí kò lè mọ̀ mí rárá nítorí aṣọ ara mi kún fún èérí, láàátọ́ mo ń gbìyànjú mo ń fọ̀ ọ́ nínú omi ṣùgbọ́n ko sí ọsẹ. Mo ń wẹ̀ ṣùgbọ́n ewé ni kànìnkàn mi; èyí tí ó burú jùlọ lára mi pátápátá ni irun orí mi ti ó kún àti ’rùngbọ̀n mi ti ó kún tó bẹ́ẹ̀ ti òun àti irun ori mi pàdé ara ti wọ́n bò mi lójú tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ṣe ni ojú mi ń dán yinrinyinrin nínú lọ́hùn-ún tí ó sì dàbí ẹni pé irun kọ́ ilé fún ojú mi ni. Nígbàa ti ó ṣe tí mo lọ sí ibi tí omi kan báyìí wà kí n baà wo ojú mi nítorí odò ni mo fi ń ṣe dígí, nígbà tí mo dé odo yìí tí mo wo ìsàlẹ̀ tí mo rí ara mi ẹ̀rù bà mí púpọ̀ nítorí kò sí ìyàtọ́ láàrin èmi àti ìnàkí rárá. Nígbà tí ó ṣe tí mo ronú mo rí i pé kì í ṣe nítorí kí ènìyàn baà rí ni ni a ṣe ń tọ́jú ara ẹni bí kò ṣe wí pé kí alára pàápàá baà gbádùn ara rẹ̀; ẹni tí ó tọ́jú ara rẹ̀ nítorí kí ènìyàn baà rí òun nìkan, ọ̀bùn ni eléyìínì. Nítorí ìdí èyí, mo pinnu àti ṣe ìtọ́jú ara mi. Kò sí ọ̀bẹ lọ́wọ́ mi rárá àfí àdá, mo sì bẹrẹ̀ sí pọ́n àdá mi. Mo pọ́n ọn fún odidi ọjọ́ kan, ẹnu rẹ̀ sì mú dáradára. Lẹ́hìn èyí, mo mú àdá mo ń fi fá ’rùngbọ̀n mi. Háà! Ohun tí ó bá nǹkan mu ni a fi ń ṣe nǹkan, àdá ṣòro láti fi fá ’rùngbọ̀n, ọ̀bẹ ni ó bá ’rùngbọ̀n mu. Ojú mi ri nǹkan ki n tóó lè fi àdá gé díẹ̀ ní ’rùngbọ̀n mi. Ṣùgbọ́n ’rùngbọ́n nìkan náà ni mo lè fi àdá fá mọ. Bí mo fé bí mo kọ̀ mo nílaáti fi irun ori mi sílẹ̀ ní kíkún kí n máa gbé eléyìínì kiri. Ṣùgbọ́n bí a bá ti mú ti irun orí mi àti ’rùngbọ̀n mi yìí kúrò nígbà tí mo ti gbé inú igbó náà pẹ́ ni inú mi kò ti bàjẹ́ mọ́: nítorí mo ti mọ ọgbọ́n àwọn àgbàlagbà wọn-ọnnì tí ó wí pé bí ó wù tí ipò ọmọ ènìyàn re ẹ̀hìn tó lórí ilẹ̀ ayé, ó yẹ kí olúwaarẹ̀ lo àǹfààní ipò náà bi ó ti yẹ, aṣiwèrè ni ẹni tí ó wí pé ti òun tán nínú ayé, bí ẹ̀mí bá ń bẹ ìrètí ń bẹ, èrò tèmi lákòókò náà ni èyí wí pé, bí ótilẹ̀ jẹ pé mo wà ní èmi nìkan ṣoṣo síbẹ̀ ẹ̀mí mi ń bẹ, ọgbọ́n orí mi yàtọ̀ sí ti ẹranko, bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè tí Ó dá ẹnu fún mi kò ní ṣàì mọ ọ̀nà tí òun Ó gbà ti Òun ó fi jẹ́ kí n máa rí nǹkan fi sí i. Bẹ́ẹ̀ ni mo pinnu lọ́kàn mi pé bi ó bá ṣe ibẹ̀ ni n ó ti lo ìyókù ìgbésí-ayé mi n ó gbíyánjú àti lò ó tayọ̀tayọ̀, ṣùgbọ́n bí Ẹlẹ́dàá mi bá wí pé kì í ṣe ibẹ̀ ni, ọjọ́ ń bọ̀ tí yóó yọ mí jáde. Ṣùgbọ́n nǹkan kan wáá ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó di ọdún kẹta gééré tí mo ṣìnà sínú igbó yìí báyìí ni: ṣe ló di ọjọ́ kan tí mo rìn lọ si inú igbó tí mo wá èèso igi lọ. Mo ri ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàpá ṣùgbọ́n n kò rí àwọn ìgbìn jù bẹ́ẹ̀ lọ, inú sì ń bí mi nítorí ìgbín tóbi ju ìjàpá nínú Igbó Olódùmarè ṣùgbọ́n àwọn ìjàpá ibẹ̀ kéré ju irú ìjàpá tí a máa ń rí lọ. Kò pẹ́ púpọ̀ tí mo ń yí igbó kiri tí òjò ńlá bẹrẹ̀ sí rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni n kò ì tí ì dé ibùdó, mo sì sá pamọ́ si inú ihò kékeré kan . Ṣùgbọ́n òjò yìí pọ̀ gidigidi bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀fúùfù ń fẹ́ kíkankíkan. Kò pẹ tí mo dé inú ihò yìí tí àgbàra òjò fi lé mi j’de tí mo sì tún sá sí ihò míràn. Nínú ihò kejì yìí, àgbàrá òjò tún lé mi jáde, òjò náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ẹ̀fúùfù sì fẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, n kò ì tí ì bá irú rẹ̀ pàdé láti ọjọ́ tí mo ti sìnà sí ibẹ̀. Nígbà tí ó pẹ́ òjò yìí dá mo sì múra mo kọ orí sí ibùdo mi, nígbà tí mo máa dé ibẹ̀, igi ńlá kan báyìí ti wó sí ọ̀kánkán ihò mi, igi náà sì ti yí òkúta kúrò lẹ́nu ihò mi. Nígbà tí mo wo inú ihò mi báyìí, ṣe ni àgbàrá òjò kún inú rẹ̀ bámúbámú, gbangba báyìí ni mo sì ń wao àwọn ìkarawun ìgbín tí mo fi ń pọ̀n omi àti igbá ẹ̀hìn ìjàpá tí mo ń lò bí àwo óunjẹ, gbogbo wọ́n dà bí ọkọ̀ lójú omi. Èyí tí ó burú ju gbogbo ọ̀rọ̀ yìí lọ ni pé iná ti kú bẹ́ẹ̀ igi ìṣáná kan ni ó kù sí inú ilé ìṣáná kí n tóó lọ, òjò sì ti pa ìṣáná náà tó bẹ́ẹ̀ tí ibi rógódó tí a fi ń ṣáná ni orí rẹ̀ ti bó sọnù. Eléyìí wáá fún mi ní ìbànújẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ sọ ìrètí nù pátápátá, mo kígbe rara mo sì wí pé:’Tèmi fi ọwọ́ Rẹ o, Ọlọ́run Ọba.’ Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀ tí mo ronu títí tí n kò mọ nǹkan tí mo lè ṣe, mo gbé àpò mi, mo gbé ìbọn mi, mo fi orí lé inú igbó, mo ń lọ. Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, mo já sí ọgbà igi eléso kan tí ó kún fún onírúurú èèso dídùn irú èyí tí n kò tí ì rí jẹ láti ọjọ́ tí mo ti ṣìnà yìí. Mo rí ìbẹ́pẹ, ọsàn, ọpẹ òyìnbó, òòro,ọ̀gẹ̀dẹ̀ pupa, òroǹbó, àti ońirúurú èèso igi mìíràn tí ó ti orígun mẹ́rẹ̀ẹrìn ayé wá sí ilẹ̀ náà. Mo wò yíká bóyá ẹni kan ló ni àwọn igi eléso wọ̀nyí n kò sì rí nǹkan kan láti fi hàn mí pé ó wà ní ìkáwọ́ ẹnikẹ́ni. Ìgbà tí ó sì jẹ́ pé nǹkan abàmì ló kún inú Igbó Olódùmarè, mo ṣebí ọgbà náà wà níbẹ̀ láti máa fi tọ́jú àwọn tí ó bá ṣìnà sí inú igbó náà ni – mo bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. Nígbà tí mo jẹun tí mo yó bámúbámú, mo jókòó, mo fi ẹ̀hìn ti igi kan báyìí, mo sùn lọ. Oorun yìí wọ̀ mi lára nítorí pé àárẹ̀ ti mú mi kí ó tóó di pé mo sùn, bí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sí lá àlá dídùn kan ni ẹnì kan déédéé jí mi. Ìgbà tí mo sì la ojú tí mo wo olúwaarẹ̀ mo rí i ó di ọmọkùnrin arẹwà kan tí ó wọ aṣọ funfun tí ó sì dé fìlà funfun tí ó sì wọ ṣòkòtò funfun oẹ̀lú. Mo kí i òun náà sì kí mi, lẹ́hìn tí ó kí mi tán ó ṣe ìbéèrè lọ́wọ́ mi báyìí, ó wí pé, ‘Kí lo ń wá láàárin ọgbà wa? Èmi náà sì dáhùn, mo ní, Ọgbà ẹ̀yin mélòó? Òun náà sì dáhùn, ó ní, ‘Ọgbà bàbá mi, Èmi náà tún béèrè, mo ní, Ta ni baba tí ó bí ọ? Òun náà tún dá mi lóhùn pẹ̀lú, ó wí pé: Baba tí ó ju baba ẹlòmíràn ni baba tí ó bí mi. Eléyìí tún mú kí èmi náà sọ̀rọ̀, mo ní, ‘Bí baba tí ó bí ọ tilẹ̀ ju baba ẹlòmíràn, ssíbẹ̀ tí ọ kò ju baba tí ó bí mi, nítorí náà jọ̀wọ́ jẹ́ kí n mọ baba tí ó tóbí náà tí ó jẹ́ baba tí ó bí ọ. Bàbá tí ó bí emi yìí ni akọ̀wédìran, baba Akọ̀wédìran sì ni Ìdákẹ́rọ́rọ́-òde, Ìdákẹ́rọ́rọ́ tó baba fún Àkọ́wédìran, Akọ̀wédìran tó baba fún èmi, Olówó-ayé, nítorí náà, kò sí baba tí ó jẹ́ baba tí ó tóbí tí ó ju baba tí ó ju baba tí ó bí mi, nítorí náà èmi bẹ̀ ọ́ tọkàkntọkàn, má ṣàìjẹ́ kí n mọ baba tí ó tóbí náà tí ó jẹ́ baba tí ó bí ọ. Níbà tí mo sọ̀rọ̀ yìí tán ọkùnrin náà wò mi, ó pòṣé kò sì fèsì ọ̀rọ̀ mi ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ó yi ojú padà ó ń lọ bí ẹni pé ó ń lọ fi ẹjọ́ mi sun ẹni kan pàtàkì ti yóò wáá jẹ mí i ìyà ohun tí mo ṣe. Ṣùgbọ́n mo ṣe àkíyèsí ibi tí ọkùnrin náà bá lọ nígbà tí ó sì ṣe díẹ̀ tí mo wo àgbègbè yíká mo rí i pé òjò tún ṣú, láìpẹ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ariwo, àṣé ariwo ẹ̀fúùfù ni. Nígbà tí ẹ̀fúùfù náà fẹ́ dé ọ̀dọ̀ mi ojú mi rí nǹkan, nítorí ẹ̀fúùfù eléyìí tún wáá pọ̀ ju èyí ó lé mi kúrò ní ihò mi lọ; nígbà ti ẹ̀fúùfù náà fẹ́ dé ọ̀dọ̀ mi nǹkan kò ṣeé fi ẹnu sọ: gbogbo igi ń fi orí lu ara wọn; ìtàkùn ń kọlu ìtàkùn, ewé gba ojú ọrùn kankan, imọ̀ ọ̀pẹ wà ni hílàhílo; igi ń rọ́ kẹ̀lẹ̀, ogunlọ́gọ̀ wọn sì ń wó lúlẹ̀ lẹ́bàá ọ̀dọ̀ mi. Inú èyí ni mo wà tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀, òjò náà sì pa mí títí mo fi ń pa eyín keke. Mo sá wọ abẹ́ ìpàǹtí síbẹ̀ àlàáfíà kò sí fún mi, mo sápamọ́ si igọ̀ igi, síbẹ̀ òjò ń fẹ́ lù mí, gbogbo aṣọ mi tutù wọ́n sì lẹ̀ mọ́ mi lára. Àkókò yìí ni mo wáá bẹrẹ̀ sí ṣe iyèméjì bóyá mo tún lè ṣe nǹkan kan lórí ilẹ̀ ayé yìí mọ́; ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì púpọ̀, èrò burúkú burúkú gbogbo ló sì ń bọ́ sí inú mi, ó sì dà bí ẹni pé kí n tìkara mi pa ara mi. Ibi tí mo tí ń ronú báyìí ni mo ti wo iwájú tí mo rí òkúta ńlá kọ̀bìtì kan. Mo múra ó di ibi òkúta yìí. Nígbà tí mo dé ibẹ̀ mmo rí ọ̀nà kékeré kan tí ó bá inú ihò òkúta náà lọ. Mo tẹ̀lée ọ̀nà yìí kí n baà wá àyè bòyá mo lè rí ibi fi orí pamọ́ sí, ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi wí pé wéré tí mo ti rìn tó bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ni mo bá ara mi nínú ilé ńlá kan tí ó tóbi gidigidi tí ó sì lẹ́wà púpọ̀. Láti ọjọ́ tí mo ti ń rìn káa kiri ayé yìí n kò bá irú ilé náà pàdé rí, ó tilẹ̀ dára ju àa[fin ọba Igbó Olódùmarè lọ. Ní orígun alápàáǹdẹ̀dẹ̀ tí wọ́n tò lọ lẹ́sẹẹsẹ. Wọ́n pọ̀ púpọ̀ n kò sì rò pé ohun ẹlẹ́mìí ni wọ́n, nítorí pé wọn kò kúrò ní ibi kan, olúkúlùkù dúró sí ipò rẹ̀ ni. Àwọn ẹyẹ wọ́nyí ń dán, wọ́n pupa bíi góòlù, àyà wọn funfun bíi fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu wọ́n dàbí eyín erin. Bí mo ti dúró tí mo ń wò wọ́n ni mo déédéé rí i tí gbogbo wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọrin lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, wọ́n ń yin Ọlọ́run lógo. Orin náà dùn tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi gbàgbé ibi tí mo wà, n kò rántí ìyà tí ó ti ń jẹ mí mọ́, mo la ẹnu sílẹ̀, díẹ̀ ló sì kù kí itọ́ já sílẹ̀ lẹ́nu mi. Ibi tí mo ti ń gbọ́ orin dídùn yìí ni mo ti rí ilẹ̀kùn kan tí ó déédéé sí ní ẹ̀gbẹ́ ògiri ni ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi bẹ́ẹ̀ kò sí ilẹ̀kùn ní ibẹ̀ nígbà tí mo kọ́ dé, nígbà tí mo sì wo ojú ọ̀nà ibẹ̀ mo rí kìnnìún kan ti ó ba ni lẹ́rù púpọ̀, ó ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi. Nígbà tí mo sì yí padà ǹjẹ́ kí n baà máa sálọ n kò rí ojú ibi tí mo bá wọ ilé náà mọ́, mo sáré síwá sáré sẹ́hìn n kò mọ èyí tí mo lè ṣe mo bá fi ara pamọ́ sí orígun kan nínú ilé náà wí pé kí kìnnìún náà máa bọ̀ kí ó kúkú pa mi jẹ. Ara kìnnìún náà jẹ́ idẹ ó ń dán yinrinyinrin ó sì lẹ́wà púpọ̀. Iyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún mi pé nígbà tí kìnnìún náà ti kù bíi ẹsẹ̀ mẹ́fà kí ó dé ọ̀dọ̀ mi ni ó ti dúró tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ké, ohùn rẹ̀ sì dàbí ìgbà tí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá àpáàrà bá sán pọ̀ lójú ọ̀run lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kò pẹ́ lẹ́hìn èyí ni mo rí obìnrin arẹwà kan, o n bọ̀ níwájú mi, mo sì ṣe àkíyèsí wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn abàmì ẹ̀dá tẹ̀lé e lẹ́hìn, wọ́n dára púpọ̀, ara wọ́n tutù nini ó ń dán bí ara ọmọ tuntun òòjọ́, bẹ́ẹ̀ ni aṣọ ara wọn ń tan ìmọ́lẹ̀ bí òòrùn ọ̀sán ganagn. Nígbà tí obìnrin yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi tí ó dé ibi tí kìnnìún idẹ nì wà, o dáhùn, ó sì wí pé: Ìwọ kìnnìún Ẹlẹ́dàá, kìnnìún idẹ, ìwọ tí a pàe fún láti máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà isà òkù, kúrò lójú ọ̀nà fún mi. Mo ti gba àṣẹ lọ́wọ́ Olódùmarè kí n ‘t’t kúrò ni òde ọ̀run. Mo ti dé odò dúdú tí í ṣe odò aró, mo ti rékọjá odò pupa tí í ṣe odò ẹ̀jẹ̀, mo sì ti sọ fún àwọn ọ̀kẹ́ àìmoye òkú tí wọ́n ń retí ìdájọ́ Ọlọ́run Ọba.’ Nígbà tí obìnrin náà wí báyìí tán kìnnìún náà bìlà sẹ́hìn. Obìnrin náà sì fa ìwé ńlá kan yọ ó fi han kìnnìún yìí, àṣé ìwé àṣẹ tí ó ní èdìdì Ọlọ́run ni èyìínì, ìgbà tí ó fi eléyìí han ẹranko náà, ilẹ̀ mì tìtì, ilẹ̀ la ẹnu, kìnnìún idẹ nì sì bá inú ihò ilẹ̀ lọ. Nígbà tí kìnnìún yìí lọ tán, obìnrin nì wọ inú ilé tí mo wà, òun àti àwọn arẹwà ti wọ́n tẹ̀lé e. Nígbà tí mo wò ó dáradára, mo rí i, ó di ìyá mi: mo bá sáré sí i kí n dì í mú ṣùgbọ́n òfo ni mo di mú, mo tún sáré sí i kí n dì mú lẹ́ẹ̀kejì òfo ni mo tún dì mú, nígbà tí mo sì sáré sí i lẹ́ẹ̀kẹta kí n dì í mú tí ó tún jẹ́ pé òfo ni mo dì mú mo bú sí ẹkún pẹ̀lú mi – Háà! Kò sí ènìyàn tí ó dà bí ìyá, obìnrin fẹ́ràn ọmọ. Ìyá mi dáhùn, ó sì wí pé: Ọmọ mi, Olówó-ayé, ọmọ mi. Ojú mi ti ń bá ọ kiri nínú ìrìnkiri rẹ. Nígbà ti ara mi kò sì gbà á mọ́ mo tọrọ àyè ní òde ọ̀run kí n baà wáá fi ojú gán-ánní rẹ. Lóòótọ́ àwọn ara ayé ni òye púpọ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀dá náà ní òde ayé tàbí ni òde ọ̀run tí ó mọ ibi tí kọ́kọ́rọ́ ìfẹ́ ìyá sí ọmọ rẹ̀ wà àfi Ọlọ́run Ọba nìkan ṣoṣo. Ọmọ tí ó ṣe àfojúdi sí ìyá rẹ̀ ti lu òfin karùn-ún Olódùmarè, eléyìínì wọ ẹ̀wù ìjàngbọ̀n sí àtàrí, ó sì fi aṣọ ìparun bora. Olówó-ayém bàbá rẹ wí pé kí n ṣe ọ́ pẹ̀lẹ́, ó ní kí n kí ọ dáadáa, òun wà nínú ìsinmi, lórí ibùsùn àǹfààní wọn dáradára. Ìwọ ọmọ mi , máṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ayé rẹ kò ní í ṣàìdára. Ọ̀lẹ ènìyàn ní í bẹ̀rù ìṣòro, ìṣòro kò sí níwájú alágbára ọkùnrin, àwọn ènìyàn pàtàkì wo ìdínà bí ẹni pé kò já mọ́ nǹkan rárá, bẹ́ẹ̀ ni òkè dà bí pẹ̀ tẹ́lẹ̀ níwájú àwọ alágbára. Máṣe bẹ̀rù ìṣòro, ọkùnrin kkì bẹ̀rù ìṣòro, oníṣòwò tí ó pàdánù lẹ́ẹ̀kan tí ó ti ìtorí bẹ́ẹ̀ wí pé òun kò ṣòwò mọ́ ti ba ayé jẹ́, àgbẹ̀ tí ohun ọ̀gbìn rẹ̀ bàjẹ́ ọ́dún kan tí ó wí pé òun kò ṣe àgbẹ̀ mọ́ ti ba orúkọ ara rẹ̀ jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ ni ibi iṣẹ́ rẹ̀ kò ṣe ibi sí ẹlìmíràn bí kò ṣe sí ara rẹ̀, nítorí onímẹ̀ẹ́lẹ́ ènìyàn kò ní lè dúró ní àwújọ àwọn èrò iwájú, wọ́n ó máa wà láàrin àwọn èrò ẹ̀hìn láéláé. Ìwọ ọmọ mi, mo gbọ́ pé ìwọ ti ní obìnrin, jọ̀wọ́ máa tọ́jú ìyàwó rẹ, ahọ́n àti enu a máa jà, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ nígbà kan rí, wí pé ahọ́n lọ wí fún ojú àti imú kí ó wáá parí ìjà òun àti ẹnu. Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni bọ́ sí ààrin rẹ àti ìyàwó rẹ bíó tí wù tí olúwaarẹ̀ súnmọ́ ọ tó; nítorí lọ́jọ́ tí ìwọ bá ti fún ẹnì kẹta láyè láti bọ́ sí ààrin yín, ìfẹ́ yín yóó dàbí omi tí ẹnì kan lọ fi akèǹgbè pọn láti odò, nígbà tí ó sì dé, ọ̀rẹ́ọkùnrin náà wá, ó gbé kúmọ́, ó lù ú mọ́ akèǹgbè, akèǹgbè náà sì fọ́, bẹ́ẹ̀ ni omi inú rẹ̀ tú jáde, ó ṣán lọ sí ìlà oòrùn, ó ṣan lọ sí ìwọ̀ rẹ̀, ó dé gúsù, ó si dé àríwá, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò si lè ló omi náà jọ mọ́. Ni ọjọ́ tí ẹnì kẹta bá ti bọ́ sí ààrin olúfẹ́ méjì ìfẹ́ náà yóò pín sí ọ̀nà ẹgbẹ̀ tàlélógún, ẹnikẹ́ni kò sì ní lè ṣà á jọ. Ìwọ ọmọ mi, má ṣe gbàgbé òótọ́-inú, ó lágbára ju òògùn lọ, òun ni àáké tí ènìyàn fi ń bẹ́ rìkíṣí , òun ni pàṣán tí ènìyàn fi ń so ìlara kọ́ sí orí igi. Òótọ́ – inú yóó maa mú ọ látti ìgbéga dé ìgbéga, yóó máa gbé ọ láti ipò ńlá dé ipò ńlá, yóó maa fi owó kún owó fún ọ, yóó máa fi ọmọ kún ọmọ, yóó máa fi ènìyàn kún ènìyàn, yóó sì ṣe ọ́ ní pàtàkì láàárin àwọn ọmọ aráyé gbogbo. Òótọ́-inú ni yóò fún ọ ní orúkọ títóbi, àwọn tí ó ti ń bú ọ lẹ́hìn yóó máa yẹ́ ọ sí lójú rẹ, àwọn tí ó tí ń ṣẹ́ èpè ní ìkọ̀kọ̀ yóó ba búrúbúrú nígbà tí ìwọ bá ṣe alábàápádé wọn, ìwọ yóó tẹ apànìyàn mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì yóò dé bá aṣnibánidárò; arírebánijẹ yóò dúró tì ọ́ ní ìgbà ìpọ́njú, ènìyàn líle yóó rọ̀ bí ọ̀gẹ̀dẹ̀ pupa, olórí-burúkú kì yóó sì dé sàkání rẹ. Nítorí ìdí èyí, Olówó-ayé, òótọ́-inúu ni kí o máa fi bá àwọn ènìyàn lò títí ìwọ yóó fi bọ́ ara ènìyàn sílẹ̀, tí ìwọ yóó pa ojú dé, tí ìwọ yóó ṣe bí èmi, tí ìwọ yóó sì wáá bá mi ní òde ọ̀run. Nípa ìyàwó rẹ, má ṣe bẹ̀rù, òun ti bímọ, ọmọ kì í sì í ṣe ọmọ lásán, ọmọ tí yóò gbé orúkọ rẹ ga lẹ́hìn ọ̀la ni. Ọmọ náà kò ní í kú ní èwe bẹ́ẹ̀ ni kò ní í dàgbà sí ìyà, apà ọmọ aráyé kò sì ní í ká a. Àkàrà-oògùn ni a ó máa pe orúkọ rẹ̀, nítorí oṣó kò ní í lè jẹ ẹ́, àjẹ́ kò ní í lè rí i gbé ṣe, bẹ́ẹ̀ ni ẹlẹ́bọlóògùn kò ní í lè pa á lára. Ìwọ ọmọ mi, n kò ní í lè sọ ju èyí lọ, àwọn ọmọ ènìyàn a máa lo àkókò bí ẹni pé kò lè tán láéláé, ṣùgbọ́n ìṣẹ́jú kan ní ìlò tirẹ̀ ni òde ọ̀run. Báyìí ni ìyá mi sọ, nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, ó mú àkàrà ńlá kan fún mi, ó wí pé: wò ó àkàrà òde ọ̀run ni mo fún ọ nì, máa jẹ ẹ́ nínú ìrìnkèrindò rẹ, eléyìí dùn ju àkàrà àwọn ọmọ ènìyàn lọ, kò lè tán bí ó ti wù kí o jẹ̀ ẹ́ tó, ṣùgbọ́n lọ́jọ́ tí o bá padà dé ilé, n ó gba ìyókù lọ́wọ́ rẹ. Nígbà tí ìyà mi parí ọ̀rọ̀ rẹ, èmi náà dáhùn, mo ní ‘Ìyá mi, irú ìfẹ́ wo ló tó yìí! Ẹni tí ó fi ìgbádùn òde ọ̀run sílẹ̀ tí ó wáá bá mi níńu àìgbádùn òde ayé! Kí ni èmi ìbá fi ọ́ wé, ìwọ ìyá mi! Ìwọ tí o níláárí ní òde ayé, ìwọ tún lọ níláárí ni òde ọ̀run. Nígbà tí ìwọ wà ní ayé, o ṣe ìtọ́jú mi bí ó ti yẹ, ó bá mi ṣiré nígbà tí ó yẹ kí a bá ọmọ ẹni ṣiré, o jẹ mi ní ìyà nígbà tí ó yẹ kí á jẹ ọmọ ẹni ní ìyà, o kò ro ẹjọ́ bàbá mi ní búburú fún mi bí àṣà àwọn obìnrin mìíràn, o kò ròyìn mi ní búburú káà kiri òde. Bí mo bá ṣe nǹkan kékeré fún ọ a máa jọ ọ́ lójú, ìwọ a sì máa sọ̀rọ̀ mi ní rere fún àwọn ènìyàn gbogbo. Ìwọ kò jẹ́ kí n tẹ́ lójú ẹgbẹ́, ìwọ kò tú àṣírí mi níwájú ọ̀rẹ́, n kò sì béèrè nǹkan lọ́wọ́ rẹ kí ìwọ kọ etí dídí sí mi. Ìwọ kò fi ebi pa mí ní bàbá, ìwọ kò tú àṣírí rẹ̀ níwájú àlejò, ìwọ kò ro ẹjọ́ bàbá mi ní ilé ìyá rẹ kí o sì mú ìtìjú bá a ní ilé àna, n kò gbọ èébú bàbá mi lẹ́nu rẹ rí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ṣẹ́ èpè fún un lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì d��bí àwọn olórí-burúkú obìnrin ti wọ́n máa ń wí tìgbéraga tìgbéraga wí pé kò sí nǹkan tí ọkọ àwọn lè fi àwọn ṣe. Ìwọ ìyá mi, bíỌlọ́run kò ti fi ọ́ sílẹ̀ ni ayé bẹ́ẹ̀ náà ni kò ni i fi ọ́ sílẹ̀ ní ọ̀run. Bí iná bá kú a fi eérú bó ojú, n ó bo ojú rẹ dáradára; bí ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá kú a fi ọmọ rẹ̀ rọ́pọ̀, n óò jẹ́ “Adérọ́pò” rere fún ọ; bí òṣùpá sì ti ń tàn káà kiri ayé bẹ́ẹ̀ ni n ó tan orúkọ rẹ káà kiri orílẹ̀-èdè ayé. N kò ní í gbàgbé ìmọ̀ràn tí ó fún mi, ọ̀nà tí ìwọ àti bàbá mi fi lé ilẹ̀ ni n ó máa tọ̀, ìfẹ́ yín sí ara yín yóò jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún mi, mo sì fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájú pé ó rọrùn kí ẹnu mi gbàgbéoúnjẹ kí ọwọ́ mi kí ó sí gbàgbé òkèlè ju pé kí n gbàgbé ohun tí ẹ ṣe fún mi. Ó dìgbà o, ìyá mi, dandan ni pé kí a pínyà lònìí, nítorí ìwọ kò sí láàárin ará ayé mọ́, ìwọ wà láàárin àwọn ará ọ̀run, kí bàbá mi fún mi, ọ̀gbẹ́ni Akọ̀wédìran, ki ẹ má ṣe gbàgbé mi kí ẹ máa bá mi bẹ Ẹlẹ́dàá kí Ó ṣe ọ̀nà mi ní rere. Ó dìgbà, ìyá mi, máa lọ sínú òkú; máa simi kúrò nínú làálàá ayé; kúrò nínú làásìgbò àwọn ọmọ ènìyàn, ni ọjọ́ tí ikú bá pa ojú mi dé, a ó máa fi ojú gán-ánní ara wa.’ Báyìí ni mo sọ sí ìyá mi, bí mo sì ti ń sọ̀rọ̀ wọn-ọnnì ni àwọn abàmì ẹ̀dá wọn-ọnnì bẹ̀rẹ̀ sí lọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, nígbà tí mo sì wo ojú ìyá mi ó bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, omi tí ó jáde lójú rẹ sì dà bí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ìyá mi ń sọkún ọmọ. Orí èmi náà wú, ọkàn mi kì sì sí nínú ayé yìí mọ́, nítorí láti ọjọ́ ti òun tilẹ̀ ti kú ni mo ti mọ̀ pé kò sí agbọ̀ràndùn tí ó dà bí ìyá, ìba ènìyàn díẹ̀ lóló ṣe bíi bàbá ẹni. Nítorí náà, nígbà tí ìyá mi fẹ́ẹ́ lọ mo tún pa guuru sí i bí ẹni pé kí n dì í mú ṣùgbọ́n òfo ni mo dì mú; mo ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì kò bọ́ sí i; nígbà tí mo sì ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kẹta, síbẹ̀ tí n kò lè dì í mú mo ké igbe ńlá mo wí tàánútàánú pé, ‘Jọ̀wọ́ ìyá mi, máa mú mi lọ; jọ̀wọ́ ìyá mi, máa mú mi lọ, àti bẹ́ẹ̀ lọ.’ Nígbà tí ó lọ tán ni mo rí i pé ó fi ẹ̀wù àti ṣòkòtò dídára kan sílẹ̀ fún mi mo sì wọ̀ wọ́n, mo ká aṣọ mi tí ó tutù mo fi í sínú àpò mi. Ìmọ̀ràn mi fún ọmọ ènìyàn ni èyí pé, kí olúkúlùkù tọ́jú òbí rẹ̀, ìba díẹ̀ ló lè ṣe bíi bàbá àti ìyá fún ni, ìgbà tí àwọn òbí bá ti fi ẹ̀hin sílẹ̀ tán, ó ku olúwaarẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Nítorí náà, nígbà tí àwọn òbi wa bá wà láyé, ẹ jẹ́ kí á máa tẹ́jú wọn, kí wọn kí ó gbó, kí wọn ki ó tọ́ fún wa. Ìgbà tí a bá ń gún iyán tí a bá ń ro ọkà ni ìgbà ìsìnkú, à ń o wó dànù ni, ẹni tí ó ti kọjá ti kọjá. Ẹ jẹ́ kí áa máa ná owó nígbà tí owó bá lè gba ẹ̀mí wọn là. Owó ìsìnkú kò lè mú òkú padà di alààyè, bí a bá ti ṣe ti ọmọlúwàbí ó ti tó, owó ànájù ń sọ wa di gọ̀ǹgọ̀sú ènìyàn ó si ń fi wá si ipò ìlábùrù, baba ọ̀bọ. Nígbà tí ìyá mi lọ tán tí mo gbé àkàrà mi tí mo jáde kúrò ní ìpàlàpálá òkúta nì, bí mo ti jáde tán ni mo rí ọkùnrin tí ó wọ aṣọ funfun tí mo kọ́ ri kí n tóó’wọ inú òkúta lọ. Ó kí mi dáadáa ó sì wí fún mi pé ọ̀gá òun ń fẹ́ẹ́ rí mi, nígbà tí mo sì béèrè orúkọ ọ̀gá rẹ̀ náà ó ní ìgbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ yóó sọ orúkọ ara rẹ̀ fún mi, mo bá tẹ̀lé e. A rìn díẹ̀ nínú igbó náà níbà tí a já sí inú ọgbà ńlá tí ó lẹ́wà gidigidi, nígbà tí ọkùnrin náà sì ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà yìí tí a wọlé tán mo rí ọ̀nà títóbi kan tí ó lọ síwájú gbọrangandan tí ó sì bá inú ilé ńlá kan lọ. Ọ̀nà yìí náà ni a ń lọ títí a fi de ilé náà. Nígbà tí mo wò yíkà mo rí i pé orí òkúta ni ilé náà wà àti pé gbogbo ẹ̀gbẹ́ ògiri rẹ̀ jẹ́ kìkì òkúta. Ọkùnrin yìí ṣí ìlẹ̀kùn ó wọlé èmi náà sì tẹ̀lé e. Nígbà tí mo dé inú ilé lọ́hùn-ún tán, ẹ̀rù bà mí àti fi ẹsẹ̀ tẹ ilẹ̀ ibẹ̀ nítorí ó dárá púpọ̀, ó ń dán yinrinyinrin, ṣùgbọ́n mo ń tẹ̀lé ọkùnrin náà bí ó ti ń lọ. Ìgbà tí mo sì tóó wọ inú ilé náà ni mo tóó ṣe àkíyèsí pé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ni, lẹ́hìn tí a ti rìn tó bí ẹsẹ̀ bàtà méjìdínlógún a dé ìdí àkàsọ̀ tí wọ́n fi ń gun òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ibẹ̀, ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí gùn ún títí ó fi dé òkè lọ́hùn-ún bẹ́ẹ̀ ni èmi náà ń gùn ún tẹ̀lé. Nígbà tí a dé òkè tán ó tún yà sí apá ọ̀tún, bẹ́ẹ̀ ni mo yà tì í,nígbà tí a sì rin bí ẹsẹ̀ mẹ́fà ó yà si apá òsì, mo sì tún yà ti í, nígbà tí a tún rin bí ẹsẹ̀ mẹ́fà lẹ́hìn èyí ó tún yà sí apá ọ̀tún, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà si tún yà tì í, lẹ́hìn eléyìí wàyí o, mo wáá rí àkàsọ̀ kékeré kan, nígbà tí òun sì gun eléyìí, mo gùn ún tẹ̀lé, nígbà tí a sì dé òkè tán mo bá ara mi ní orí òrùlé tí ó tẹ́jú pẹrẹsẹ tí ó si jẹ́ òkùta pátápátá. Ní ààrin òrùlé náà ni mo bá ọkùnirn títóbi kan tí orí rẹ̀ pá tí ‘rùngbọ̀n rẹ̀ sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó gba ìdajì orí òkúta náà kankan, ó ń mu ìkòkò ńlá kan. Ẹ̀rú ọkùnrin náà bà mí àfi bí mo bá máa purọ́, wéré ni mo dọ̀bálẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀, bí mo fẹ́ bí mo kọ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí tẹríba, n kò lè wáá rí ọ̀ràn ọ jàre. Lẹ́hìn eléyìí ọkùnrin náà wí fún mi kí n dìde ó sì la ẹnu rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rtọ̀ í sọ, ó wí pé, ‘Dìde ìwọ ọmọ ènìyàn, èmi ni Baba – onírùngbọ̀n – yẹ́úkẹ́, ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta. Ọjọ́ pẹ́ tí mo ti dé ìhín, ó ju ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọdún lọ. Ibib tí mo wà yìí ni ìpẹ̀kun ayé, ògiri tí ó sì yí ilé mi ká ni ó pín mi ìyà pẹ̀lú àwọn ara ọ̀run, nínú àgbàlá mi yìí pẹ̀lú, púpọ̀ nínú àwọn ara ọ̀run ni a jọ ń ṣiré pẹ̀lú ara wa, nígbà tí ìwọ bá sí jẹun tán, n óò mú lọ si ilé ẹbọra pàtàkì nì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ikú, nítorí bí òun ti ni ilé kan sí òde ọ̀run bẹ́ẹ̀ ni ó tún ni ilé kan sí ọ̀hún nì, níbi tí ó jẹ́ agbedeméjì ayé òun ọ̀run. Bí a bá kí ẹbọra eléyìínì tán n óò mú ọ lọ sì ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ nítorí ọ̀tọ̀ ni obìnrin náà ń gbé, ẹbọra tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àrùn, oníròbìnújẹ́ obìnrin. Ìbátan mi ni òun í ṣe ni ìdí ìyá mi. Bàbá obìnrin náà lówó gidigidi àti kékeré ni wọ́n sì ti fi àkẹ́jù ba Àrùn jẹ́ níwọ̀n ìgbà tí kò sì ti sí ẹni tí ó lè fẹ́ ẹ láàárin àwọn ọmọ ènìyàn, iwin kan ni ó fẹ́ ẹ tí ó gbé e lọ sí òde ọ̀run. Ṣùgbọ́n ìwà rẹ̀ burú tó bẹ́ẹ̀ ó sì dá rìkiṣí sílẹ̀ ní òde ọ̀run. Òun jẹ alágàbàgebè obìnrin, àwọn ẹ̀dá ọ̀run sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ ẹ̀hìn sí ara wọn. Nígbẹ̀hìn, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní òde ọ̀run, àwọn tí ó fẹ́ràn obìnrin náà dá rúdurùdu sílẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀ rọ̀ náà dé etí Ọlọ́run Ọba. Ìgbà tí Àrùn bẹ̀rẹ̀ sí ro ẹjọ́ níwájú Ẹni tí Ó dá a, ó sọ̀rọ̀ àìyẹ jáde lẹ́nu, eléyìínì náà lo sì mú kí Olódùmarè lé e jáde ni òde ọ̀run. Lẹ́hìn èyí, ó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, fún odidi ọdúnmẹ́rìnlélógójì ni Àrùn sì fi ń ṣe ìyàwó Èṣù tí ó jẹ́ ọba ìlú Ọ̀run Àpáàdì ṣùgbọ́n nígbà tí ó di oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ kọkàanlá, ní ọdún kẹrìnlélógójì, ó sá kúrò ní Ọ̀run Àpáàdì nítorí ó wí pé èéfín iná Ọ̀run àpáàdì pọ̀ jù ní ti òun. Ẹyìn èyí ni ikú ssì tọrọ àyè lọ́wọ́ Ọlọ́run kí ó jẹ́ kí òun fẹ́ ẹ kí obìnrin náà baà lè jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún òun ni ibi iṣẹ́ òun. Nítorí náà, ìwọ ọmọ ènìyàn, lẹ́yìn ìgbà tí ìwọ bá jẹun tán, gọngọ máa sọ, múra kí o fún ṣòkòtò rẹ̀ le, nítorí ójú rẹ ń bọ̀ wáá rí nǹkan. Mo kí ọ púpọ̀, o kù ìrìn, o kú làásìgbo òde ayé, o kú ìrìnkiri inú aginjù, o kù ọjọ́ rírí jẹ, o kú ọjọ́ àìríjẹ, àwọn ènìyàn rẹ ńkọ́? Àlàáfíà kọ́ ni ìyàwó rẹ wà? O kú wàhálà Igbó Olódùmarè, ibùgbé ohun àràmọ̀dà ayé gbogbo. Dájúdájú ìwọ ti bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyọnu pàdé, òòrùn ti pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán, ìwọ sì ti sọ òṣùpá di àtùpà ní ìgbà òru, ṣùgbọ́n lórí ìwọ̀nyí, mo wífún ọ, ìwọ ọmọ ènìyàn, ìforítì lẹbọ. Bí ìwọ bá ní ìforítì, ìyókù kéré, àsẹ̀hínwá-àsẹ̀hìnbọ̀ ìwọ ń bọ̀ wáá jèrè ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ lórí ayé, eléyìínì si ni èyí pé, kí olúwaarẹ̀ má ṣe lo ayé ara rẹ̀ fún ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n kí ó lò ó fún àwọn ẹlòmíràn, tó bẹ́ẹ̀ tí, nígbà tí oúwaarẹ̀ bá pa ojú dé, àwọn ọlọgbọ́n kò ní ṣàì máa wí lẹ́hìn rẹ̀ pé, Ọkùnrin náà ṣe ìwọ̀n tí ó lè ṣe. Báyìí ni ọkùnrin náà sọ, ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì wọ inú ọkàn mi lọ, nígbà ti èmi náà máa fún un ní èwsì, mo mí kanlẹ̀, mo húkọ́ ‘kẹ̀hẹ̀’, kí ó ma baà sí ohun ìdíwọ́ ni ọ̀nà ọ̀fun mi. Lẹ́hìn èyìínì mo dáhùn mo wí pé: Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ mi ọ̀wọ́n, ìbá ṣe pé ìwọ dé inú mi ni, ìwọ ìbá mọ̀ pé inú mi dùn ju iyọ̀ òyìnbó lọ. Mo yọ̀ púpọ̀ pé mmo mọ̀ ọ́ lónìí, ọ̀rọ̀ tí ìwọ sì sọ ń bẹ ni ìsàlẹ̀ odò ikùn mi. Ó yà mi lẹ́nu láti gbọ́ pé ìwọ ssúnmọ́ òde ọ̀run tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ògiri kan ni ó pín ilé rẹ ní ìyà pẹ̀lú ọ̀run. Àkókò tí mo bá sì fi wà lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú, n kò ní í gbé ẹbọ kọjá oríta, n kò ni í kọjá ògiri rẹ, nítorí n kò fẹ́ẹ́ déédéé lọ sí ọ̀run lọ́sàn-án gangan. Nípa ti oúnjẹ ti ìwọ sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú, mo dúpẹ̀ lọ́wọ́ rẹ gidigidi, o kú àlejò mi. Ebi kò ì tí à mí nísisìyí, ìgbà tí a bá simi díẹ̀ n óò wáá jẹun. Nípa èyí tí o sì béèrè nípa Igbó Olódùmarè, n kò lè purọ́ fún ọ, ojú mi rí nǹkan. Ẹ̀fúùfù fẹ́ títí mo fi fẹ́rẹ̀ ṣe àìsàn; bẹ́ẹ̀ ni òòrùn pa mi títí ara mi fi gbóná bí iná alágbẹ̀dẹ. Nípa ti ìyàwó mi, mo lè wí fún ọ pé ìyàwó mi ń bẹ; nípa ti àwọn ènìyàn mi, mo lè wí fún ọ pé alàáfíà ni àwọn ènìyàn mi wà; bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé, ọjọ́ pẹ́ tí mo ti fi àwọn ènìyàn mi wọ̀nyí sílẹ̀, síbẹ̀ àdúrà tí ọmọ èn[[iyàn bá gbà fún ara rẹ̀ ni Olódùmarè ń bá a gbà, ọkàn ẹni ni àlúfáà ẹni. Ṣùgbọ́n ìwọ ọ̀rẹ́ mi, ó yà mi lẹ́nu láti gbọ́ orúkọ àwọn aládùúgbò rẹ, mo sì ní ìrètí wípé nígbà tí mo bá rí àyè n ó lọ mọ̀ wọ́n ṣùgbọ́n n kò rò pé mo lè rí wọn lónìí mọ́ nítorí ilẹ̀ ń ṣú lọ, mo sì rò pé ó kúkú yẹ kí ìwọ àti èmi jọ máa gbádùn ara wa lónìí, bí ó bá di ọ̀la a ó lọ kí àwọn aládùúgbò rẹ. Olówó-ayé ni orúkọ mi, bàbá mi sì ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akọ̀wédìran. Ọjọ́ abámì sì ni ọjọ́ òní, tí ọkùnrin pàdé ọkùnrin, tí mo ṣe alábàápàdé rẹ; ìwọ ọ̀gbẹ́ni àgbàlagbà, Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́, ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta.’ Nígbà tí mo parí ọ̀rọ̀ mi tán gbogbo wa múra láti sọ̀ kalẹ̀ sí ìsàlẹ̀ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì náà, ṣùgbọ́n nígbà tí Baba-onírùngbọ̀n dìde, ẹnu yà mí gidigidi: nítorí ìgbà náà ni mo túbọ̀ wáá rí ‘rùngbọ̀n ńlá yìí tí ó gba gbogbo orí òkúta. Nígbà tí ọkùnrin náà sì ń sọ̀ kálẹ̀ òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì rẹ̀ mo wí fún un, mo ní, ‘Baba-onírùngbọ̀n mi ọ̀wọ́n, jẹ́ kí n bá ọ kó díẹ̀ ni ‘rùngbọ̀n rẹ.’ Òun náà fèsì, ó ní, ‘Olówó-ayé mi ọ̀wọ́n, kọjú sí èyí tí ó bá ọ, mú ojú kúrù ní ‘rùngbọ̀n mi’. Nígbà tí ọkùnrin náà sì wí báyìí èmi náà kò tún sọ̀rọ̀ nípa ‘rùngbọ̀n onírùngbọ̀n mọ́, mo fi onírùngbọ̀n silẹ̀ kí ó máa gbé ‘rùngbọ̀n lọ. A ṣiré títí ilẹ̀ ọjọ́ náà fi ṣú, inú èmi náà pàápàá tilẹ̀ dùn púpọ̀ lákòókò náà nítorí, lọ́nà kínní, ọjọ́ pẹ́ tí mo ti rí ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ sí kí á sì jọ máa wọlé kí á jọ máa jádde, lọ́nà kejì, ọjọ́ pẹ́ tí mo ti rí aṣọ dáadáa wọ̀ mọ bẹ́ẹ̀ ni ìgbà tí mo sì dé ọ̀dọ̀ Baba-onírùngbọ̀n ni mo ti wọ ṣòkòtò àti ẹ̀wù tuntun tí ìyà mi wáá mú fún mi, àwọn aṣọ náà sì ba mi mu púpọ̀ nítorí oníṣọ̀nà òde ọ̀run ni ó rán wọn: èmi náà bẹ̀rẹ̀ si ṣe fáàrì lọ́dọ̀ Baba-onírùngbọ̀n mo ń yan tẹ́nki-tẹ́nki kiri.’ ỌJỌ́ KEJÌ LỌ̀DỌ̀ BABA-ONÍRÙNGBỌ̀N-YẸ́ÚKẸ́ Ẹ́NI TÍ Ń GBÉ IBI GEGELE ÒKÚTA Nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì tí a jẹun tán, Baba-onírùngbọ̀n rán mi létí nípa ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó wí pé kí a lọ kí, ó sì dàmọ̀ràn pẹ̀lú pé ilé Ikú ni kí á kọ́kọ́ lọ, a sì múra a ń lọ. Èyí tí ó kọ́ yà mí lẹ́nu ni èyí pé, ojú ọ̀nà ilé Ikú kún fún ẹ̀jẹ̀ gbogbo, àwọn ewéko tí ó sì wà lójú ọ̀nà kún fún ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú, síbẹ̀síbẹ̀ Bab-onírùngbọ̀n ń tẹ orí ẹ̀jẹ̀ náà lọ láìbìkítà, ‘rùngbọ̀n rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí pa mí lẹ́rìn-ín bí ó tí ń wọ́lẹ̀ guruguru, tí ó ń la inú ẹ̀jẹ̀ lọ. Ẹ̀rù nǹkan kaan kò tilẹ̀ wáá bà mi lákòókò náà mọ́ nítorí ẹni tí ó ti kúrò láàrin àwọn ọmọ ènìyàn tí ó fi orí lé ọ̀nà Igbó Olódùmarè tí ó dé ọ̀hún tán tí ó tún ń wá ilé Ikú kiri, eléyìínì ti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹekẹ̀ bọ ara rẹ̀ lẹ́sẹ��, ó so ẹ̀wọ̀n mọ́ ara rẹ̀ ní ìbàdí, ó fún omi ata sí ojú, ó sì ń wá ìjàǹbá káàkiri òde – bẹ́ẹ̀ ni Baba-onírùngbọ̀n ń lọ tí èmi tí kò ní ‘rùngbọ̀n náà ń tẹ̀lé e. Nígbà tí ó ṣe a yọ sí ilé Ikú, a ń wwo ilé ná lọ́kàn-án-kan, nígbà tí mo sì súnmọ ọn mo rí òkìtì ńlá méje tí ó bá ojú ọ̀run lọ wọ́n kún fún egungun. Òkìtì kìínì kìíní kún fún egungun ènìyàn, èkejì kún fún egungun ẹranko, ẹ̀kẹta jẹ́ ti ejò, ẹ̀kẹrin jẹ́ ti ẹja, ẹ̀karùn-ún jẹ́ tí ẹyẹ, ẹ̀kẹfà jẹ́ ti àwọn kòkòrò, bẹ́ẹ̀ ni èkeje jẹ́ ti àwọn eṣinṣin, ṣùgbọ́n òkìtì keje yìí kò kúkú ní egungun bí i tí àwọn ìṣáájú, ó ní iṣan tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ báyìí, àwọn wọn-ọnnì ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí egungun. Nígbà tí a rìn súnmọ́ ilé náà díẹ̀ Ikú yọ jáde láti inú ilé, ó ń bọ̀ wáá pàdè wa. Òun wà ní ìhòhò gidigbi. Ó mú kùmọ̀ ńlá kan sí ọwọ́ òsí, ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún mú agbárí ènìyàn kan: nítorí ẹ̀dá búburú ni, a máa fi agbárí ènìyàn mu omi. Bí abàmì ẹ̀dá náà ti jáde láti inú ilé rẹ̀, Baba-onírùngbọ̀n kọjú sí mi, ó wí pé; ‘Wò ó, ẹ̀dá pàtàkì náà ní ń bọ̀ lọ́hùn-ún nì, Ikú, ẹni tí ilé rẹ̀ ń bẹ lágbedeméjì ayé òun ọ̀run. Ẹ̀dá burúkú ni Ikú, kò sì ní ẹran kan ṣoṣo lára, ó kún fún kìkì egungun, ojú rẹ̀ tóbi tó àwọ oúnjẹ, ó dà bí òṣùpá, ó ń pupa bí iná, ó sì ń yí bí ìgbà tí èèso igi tí ó tóbi bá doríkodò tí atẹ́gùn kékeré ń fẹ́ ẹ sí ihìn àti sí ọ̀hún. Ehín ẹnu rẹ̀ dà bí tí kìnnìún, ó ń pọ́n kankan: nítorí Ik’;u kò gbádùn iṣu bẹ́l ni kò gbádùn ọ̀gẹ̀dẹ̀, kò gbádùn ilé bẹ́ẹ̀ ni kò gbádùn ẹ̀fọ́, òun gbádùn ẹran ènìyàn ju ohun gbogbo lọ. Ikú ń bọ̀ lọ́dọ̀ wa. Bab-onírùngbọ̀n àti èmi náà sì ń tọ̀ ọ́ lọ. Bígbà tí a pàdé rẹ̀ ó kí Baba-onírùngbọ̀n ṣùgbọ́n kò kí mi. Lẹ́hìn èyí, ó yípadà ó ń bá ọ̀nà ilé rẹ̀ lọ, àwa náà ń tẹ̀lé e, bẹ́l ni òun àti Baba-ońrùngbọ̀n ń sọ̀rọ̀ bí wọ́n tí ń lọ, wọn kò sì sọ̀rọ̀ sí mi. Nígbà tí a dé ilé rẹ̀ lọ́hùn-ún tí mo fẹ́ẹ́ jókòó, Baba-onírùngbọ̀n ṣẹ́ ojú sí mi pé kí n má ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùggbọ́n ohun tí ó yà mí lẹ́nu jùlọ nínú ilé náà jẹ́ méjì. Èkínní ni pé ni ẹ̀gbẹ́ ògiri ilé náà ní apá ọ̀tún orúkọ gbogbo àìsàn tí ó lè pa ènìyàn ló wà nìbẹ̀ àti èyí tí ó kéré pátápátá lójú ẹni àti èyí ó ba ni lẹ́rù púpọ̀, gbogbo orúkọ wọn pé ṣánṣán sí ẹ̀gbẹ́ ògiri. Nígbà tí mo sì wo ìsàlẹ̀ orúkọ wọn-ọnnì mo rí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí wọ́n kọ tí ó sí tóbi gàdàgbàgadagba. Èerí ara, èérí ibùgbé, èérí aṣọ, èérí oúnjẹ, èérí ẹ̀fúùfù, èérí àpòlòkú ẹni, àìyàgbẹ́ lákòókò, àti ìwà àìbikítà nígbà tí àìsàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ – àwọn wọ̀nyí ni ó ń mú èyí tí ó pọ̀ jù nínú àwọn ọmọ ènìyàn kúrò ní òde ayé ní ìgbà òwúrọ̀ àti ní ìgbà ọ̀sán gangan wọn.’ Ohun kejì tí ó yà mí lẹ́nu ni àwọn ènìyàn méje tí mo bá nínú ilé náà ní torí bí mo ti ṣe rí wọn jọ mí lójú gidigidi. Èyí èkínní jókòó lórí àga didáda kan, ó wọ ẹ̀wù àrán àti ṣòkòtò àrán ó sì dé fìlà àrán tí ó dà bí adé bẹ́ẹ̀ ni bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí góòlù, ẹ̀wù pẹ̀lú ṣòkòtò rẹ̀ sì lẹ́wà púpọ̀, ọkùnrin náà dà bí ọba, ó sì yà mi lẹ́nu láti bá irú arẹwà bẹ́ẹ̀ nínú ilé òbùrẹwà ẹbọra. Èyí èkejì kọ́ jókòó nígbà tí a wọ ibẹ̀ ṣùgbọ́n lẹ́hìn eléyìí ó dìde, lẹ́hìn èyìínì pẹ̀lú ó ń sáré káà kiri inú ilé, lẹ́hìn eléyìínì ó ń rìn, lẹ́hìn èyí pẹ̀lú ó tún jòkòó, ara rẹ̀ kò sì balẹ̀, ó dà bí ẹni tí ń bẹ̀rù ohun ńlá kan. Mo wáá ṣe àkíyèsí pé ìwé pẹlẹbẹ kan wà ní oókan-àyà rẹ̀, ohun tí wọ́n sì kọ sí inú ìwé náà ní èyí: ‘Mọ́tò kò ní ìbátan, rélùwé kò ní ìyàwó, bẹ́ẹ̀ ní alùpùpù kò ń tijù ẹnikẹ́ni, ẹni tí ó bá fi ojú di irin á bá irin lọ.’ Èyí ẹ̀kẹta wà ní ìdúró, ó wọ ṣòkòtò tuntun àti ẹ̀wù tuntun ṣùgbọ́n ó dé fìlà àgbàlagbà, fìlà náà sì burú ó dà bí fìlà ayé àtijọ́. Ìwé kan wà ní oókan-àyà ọkùnrin náà ohun ti wọ́n sì kọ sí ibẹ̀ ni èyí: ‘Ní ọjọ́ tí Ẹlẹ́dàá bá máa ṣe idájọ́ ẹ̀dá a óò dá ọ sílẹ̀ a ó sì fi ìyà jẹ baba ńlá tí ó bí ọ. Èyí ẹ̀kẹrin jẹ́ obìnrin, ó sùn sí orí ẹní kan ó ń yí ní ilẹ̀ kiri bí ẹni pé ó ní ìrora ńlá kan, àkísà ní aṣọ tí ó fi bora, lára àkísà náà wọ́n sì kọ ìwé yìí sí i. ‘Alágàbàgebè yóò máa tí orí ìtìjú dé ìtìjú, òun kì í ṣe ẹni òkè, yóó maa wà láàrin àwọn èrò ẹ̀hìn láéláé. Èyí ẹ̀karùn-ún wà ní orí àkàsọ̀ kan tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtẹ̀gùn, ó jókòó lórí àtẹ́gùn tí ó wà lóké pátápátá nígbà tí a wọlé. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe ó bọ́ sí àtẹ̀gùn tí ó tẹ̀lé èyínì, nígbà tí ó tún ṣe ó tún bbọ́ sí ìsàlẹ̀ eléyìíni pẹ̀lú, nígbà ‘t ió tún ṣe ó tún bọ́ sí ìsàlẹ̀, bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ kí á tóó kúrò nínú ilé náà orí ilẹ̀ ló jókòó lé. Mo ṣe àkíyèsí ìwé kan tí ó wà ní oókan-àyà rẹ̀, ohun tí wọn kọ sí ibẹ̀ sì ni èyí: ‘Bí iré bí iré ẹni tí ó ń jáfara bá ara rẹ̀ láàárin àwọn èrò ẹ̀hìn, bí iré bi iré aláfara bá ara rẹ̀ ní ọ̀run alákejì. Èyí ẹ̀kẹfà jókòó lórí àga dáradára, ó da aṣọ bora, ojú rẹ̀ ń dán, ara rẹ̀ tutù, eyín rẹ̀ funfun, ọkàn rẹ̀ balẹ̀, aṣọ tí ó fi bora náà sì dára púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun náà lẹ́wà gidigidi. Ará rọ̀ ọ́ ju Ikú lọ, òun si dà bi ọ̀gá nínú ilé náà. Ní oókan-àyà rẹ̀ ni wọ́n kọ àkọlé yìí sí: ‘Ọkàn olódodo balẹ̀ bí ọkàn ẹni tí kò hùwà ìbàjẹ́ sí ọmọ nìkejì, tí kò sì ṣe ohun ìkọ̀kọ̀ pamọ́ sí ọwọ́ ẹni ẹlẹ́ni, ọkan olódodo funfun gbòò, ara rẹ tutù bí ara ewéko etí omi, olódodo dúró gbọnin bí òkè ńlá. Èyí èkeje wà nínú ipò tí ó ba ni lẹ́rù gidigidi. A bá a nínú àwọn kan báyìí tí wọ́n fi irin ṣe, ó dàbí àwọn àwọn apẹja, ó ní igun mẹ́rin, ó dúró ó sì dà bí ilé fun ọkùnrin náà. Nígbà tí a dé ibẹ̀ iná kan bẹ̀rẹ̀ sí jó nínú ibi tí ọkùnrin yìí wà, ó si ń jó o, ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí kígbe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ó ń gbin, ó ń pòṣé, gbogbo àyíká ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì mú kí ilé Ikú ba ni lẹ́rù gidigidi. Lẹ́hìn igbe tí ọkùnrin yìí ń ké tí iná kú tán ni mo rí ọwọ́ kan tí ó di pàṣán mú bẹ́ẹ̀ n kò sí rí ẹni tí ó ni ọwọ́ yìí, ọwọ́ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi pàṣán na ọkùnrin tí ń bbẹ nínú ìhámọ́ náà. Nígbà tí ó ṣe, pàṣán yìí gbó, mo sì tún rí ọwọ́ yìí tí ó di àáké mú tí ó tún ń lé ọkùnrin náà kiri nínú àwọn ó ń ṣá àáké mọ́ ọn lára, ẹ̀rù bà mí nígbà tí mo ń rí ojú ọgbẹ́ tí mo ń rí àgbàrá ẹ̀jẹ̀ tí mo sì ń fi ojú mi rí egungun ara. Lẹ́hìn tí àáké yìí dúró, mó tún rí ọwọ́ yìí, ó lọ ata ó sì mú ata náà ó ń fi ra ojú ọgbẹ́ ọkùnrin yìí, ọkùnrin náà sì tún ń sá kiri, àyà mi sì já tó bẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ sá jáde. Ìgbà tí ó tún ṣe, àfi bí mo tti ri omi gbígbóná tí ó ń rọ́ láti òkè lu ọkùnrin náà tí ara rẹ̀ sì bó fẹ́lẹfẹ̀lẹ; bí omi yìí sì ti ddáwọ́ dúró ni ẹ̀wọ̀n kan wá láti òkè tì ó dè é, inú èyí ni a sì fi í sí títía fi jáde nínú ilé ẹ̀dá tì kò ní ìtìjú, Ikú ẹni tí ń gbé agbedeméjì ayé òun ọ̀run. Kí n máa bá ọ̀rọ̀ mi lọ, nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀ tí a ti dé ilé Ikú ni Baba-onírùngbọ̀n fi mí hàn án, ó ní, ‘Ìwọ ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, Ikú ẹni tí ilé rẹ̀ ń bẹ́ lágbedeméjì ayé òun ọ̀run, láì-ṣe-àníàní, ìwọ kò ní ṣáì ṣe àkíyèsí ẹni tí ó tẹ̀lé mi, bí a kò bá sì ní í purọ̀, ìwọ kò ní ṣaìfẹ́ẹ́ mọ irú ènìyàn tí òun jẹ́ pẹ̀lú – òótọ́ ni: ọkǹuirn tí ìwọ ń wò lẹ́hìn mi nìm ọ̀rẹ́ mi ni; ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ènìyàn sí ni pẹ̀lú. Òun ní Olówó-ayé, tí ó wá sí Igbó Olódùmarèwáá ṣe ọdẹ. Àná yìí náà ló dé ọ̀dọ̀ mí, láti ìgbà tí ó sì tí dé ọ̀dọ̀ mi yìí ńkọ́, òun ní mo ti ń ṣe àkíyèsí wí pé gbajúmọ̀ ènìyàn ni, bí a bá tilẹ̀ wí pé kí á sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin náà tó bí ó ti níláárí ni, a kò bá tí wí pé igba ojú ni ó mọ̀ ọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò bá pé ẹgbẹ̀ta ojú ni pẹ̀lú. Òun ni a bá máa pè ní, Olówó-ayé ẹgbẹ̀rún-ojú-mọ̀-ọkùnrin. Ki n má fa ọ̀rọ̀ mi gùn bí ilẹ̀ bí ẹní, mo ní ayọ̀ láti sọ fún ọ pé, àti ìgbà tí ọkùnrin náà ti dé ni a ti ń ṣiré tí a ń gbádùn ara wa, níwọ̀n ìgbà tí ó si ti jẹ́ pé, ìwọ ọ̀rẹ́ mi, tí oj jẹ́ aládàágbò mi ni o tì ń ṣe ìtọ́jú mi ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá kí òun tóó dé ìhín, mo tànmọ́ọ̀ pé ohun yíyẹ ni, ẹ̀tọ́ sì ni pẹ̀lú, wí pé kí èmi àti òun wá, kí àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fi ojú gán-ánní ara wa. Nítorí náà ènìyàn pàtàkì ni Olówó-ayé ẹbọra pàtàkì sì ni ìwọ náà pẹ̀lú, ẹ kò sínínú ọ̀rẹ́ tí ènìyàn lè náání, kí Olódùmarè máṣe náání ẹnikẹ́ni nínú wa; o kú àtijọ́ o, ó pẹ́ díẹ̀ tía ti rí ara wa mọ, mo rò pé o ń rí nǹkan ṣe nǹkan, èmi náà ń bá ìgbésí-ayé mi lọ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ẹlẹ́dàá mi, èmi náà, ọ̀rẹ́ rẹ àtàtà, Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́, ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta.’ Báyìí ni Baba-onírùngbọ̀n sọ nípa mi, bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ wọn-ọnnì, èmi náà ti gbàgbé pé ilé Ikú ni mo dúró sí, èmi náà dúró bí ènìyàn pàtàkì, mo fi ọwọ́ tẹ ìbàdí, bí ènìyàn pàtàkì tì ń ṣe níwájú ènìyàn pàtàkì, mo dúró bí alágbára tí í dúró níwájú alágbára. Bí ó sì tí ń sọ̀rọ̀ wọn-ọnnì pẹ̀lú, èmi náà ń mi orí mi bí àmì láti fi hàn wí pé mo ń gbádùn ọ̀rọ̀ ẹnu ọ̀rẹ́ mi: nítorí ẹni tí ó gbé ni gun orí ìtẹ́ ló tí wí pé kí á hùwà ènìyàn ńlá, ẹni tí ó gbé ẹ̀wù sányán bọ ni lọ́rùn ló ti wí pé kí a hùwà ènìyàn pàtàkì, bí ọ̀rẹ́ mi ti ń sọ̀rọ̀ mi dáradára wọn-ọnnì, èmi náà rọra ń fi ohùn ìsàlẹ̀ wí kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí i létí wí pé: ‘Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́, ọọ kú ọmọ, Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́, ọọ kú ọmọ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.’ Nígbà tí ọkùnrin náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, dípò kí Ikú fèsì kúkúrú, ó fèsì tí ó gún gbọọrọ. Ohùn ẹ̀dá náà ba ni lẹ́rùn gidigidi, nígbà tí mo sì kọ́ gbọ́ ọ, ó dà bí ìgbà tí àpáàrà ńlá bá sán lójú ọ̀run, ọ̀nà ọ̀fun rẹ̀ si ń kù bí ìgbà tì òjò ńlá bá ń fẹ́ẹ́ rọ̀. Ikú wí pé: Èmi ni Ikú, èmi pàtàkì tí í ṣe ìránńṣẹ́ Olódùmarè, àáké Ọlọ́run Ọba, tí ń gbé àwọn ènìyàn lulẹ̀, tí ń hú gbòǹgbò ẹni ńlá, tí ń gba baba lọ́wọ́ oníbaba, tí ń gba ìyá lọ́wọ́ oníyàá, mo ti gba ọmọ lọ́wọ́ ọlọ́mọ; mo ti gba ènìyàn lọ́wọ́ elénìyàn; mo ti gba ọkọ lọ́wọ́ ọlọ́kọ; mo ti gba ìyàwó lọ́wọ́ oníyàwó, mo ti pín olùfẹ́ ní ìyà; mo ti gba ọ̀rẹ́ lọ́wọ́ ara wọn; mo ti sọ gbajúmọ̀ lẹ́rù kalẹ̀; mo ti mú àyípadà bá olówó; mo ti fẹ́ ojú bọ̀ọ̀kinní kù; àkùkọ ti kọ lẹ́hìn alágbára; mo ti mú arẹwà kúrò lórí ilẹ̀; mo ti sọ àwọn ọlọgbọ́n di èrò inú pósí; mo ti pa ojú àwọn ènìyàn pàtàkì dé, àti gèǹdè, àti àgbàlagbà, ọkùnrin, obìnrin, dúdú, funfun, pupa; gbogbo wọ́n tí ṣubú níwájú mi. Ẹni tí ó ti ń wé gèlè rí, di ẹni tí kò lè wé gèlè mọ́, ẹni tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní àwùjọ, di ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ ní àwújọ; bẹ́ẹ̀ ni nínú ọlá tí Ọlọ́run Ọba fi fún mi mo ti pa àwọn ọmọ aráyé lẹ́kún, mo ti sọ wọ́n di ẹni tí ń gbé ara ṣánlẹ̀, mo ti sọ wọ́n di ẹni tí ń doríkodò, tí ń pòṣé, tí ń sọkún, tí ń sì ń mí ìmí ẹ̀dùn kanlẹ̀, emi náà, ẹbọra pàtàkì ńlá nì, Ikú ẹni tí ilé rẹ́ ń bẹ lágbedemejì ayé òun ọ̀run. Ìwọ ọmọ ènìyàn, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ lónìí tí ìwọ wáá kí mi ní ilé mi, mo sì fẹ́ẹ́ rán ọ sí àwọn ọmọ aráyé, lónìí yìí, ní ọjọ́ kẹrìndín-lógún oṣù kọkànlá, ní ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀wá ọdún ó lé mẹ́tàlálógójì lẹ́hìn ikú Olúwa wa, wí pé, kí àwọn ọmọ ènìyàn jọ̀wọ́ ṣe àforíjì, kí wọ́n dín iṣẹ́ mi kù díẹ̀ nípa ìtọ́jú ara wọn. Àwọn tí ìwọ rí nínú ilé mi wọ̀nyí, Ọlọ́run Ọba ni Ó fi wọ́n fún mi; ọ̀kan nínú wọn kì í gbé ilé mi, òun wá láti wáá bẹ̀ mí wò lónìí ni nítorí òde ọ̀run ni ilé rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn mẹ́fà tí ó kù jẹ́ tèmi, Ọlọ̀run Ọba sì ti pa á láṣẹ fún mi pé kí n máa fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn ọmọ aráyé ti wọ́n bá dé sàkáání mi. Fetí sílẹ̀ kí o gbọ́ ìtàn wọn, kí o gbọ́ ohun tí ó jẹ́ kí wọ́n fi ayé sílẹ̀ tì wọ́n sì fi di èrò ọ̀run: Èyí èkínní di arúgbó kí ó tóó kúrò nínú ayé, kò hùwà ibi, kò ṣèké, kò ba orúkọ ọmọnìkejì jẹ́, kò di rìkíṣí mọ ẹni ẹlẹ́ni, kò tọ babaláwo lọ nítorí àti ba ti ọmọnìkejì jẹ́, kò wí pé kí ni Ọlọ́run máa ṣe, kò búra èké, kò ṣe olè, kò yáájú sí àgbàlagbà, bẹ́ẹ̀ ni kò hùwà ibi kan ṣsoṣo. Nítorí ìwọ̀nyí, nígbà tí o di ẹni à��dọ́rin ọdún, Ọlọ́run Ọba pínnu pé ó níláti kúrò nínú ìbànújẹ́, ayé kí ó máa jẹ ìgbàdùn ọ̀run, òní yìí nìkan ṣoṣo ni ó wáá kí mi, gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ fún ọ lẹ́ẹ̀kan, kò ní í pẹ́ padà lọ sí òde ọ̀run. Èyí èkejì fi ayé sílẹ̀ kí ó tóó di ìgbà tí Olódùmarè dá fún un: ó lójú kò fi ríran; ó ní ọgbọ́n kò lò ó; ó sì fi òmùgọ̀ ba ìgbésí-ayé ara rẹ̀ jẹ́. Nígbà tí ó bá ń ṣe fáàrí, kò ní í sá fún mọ́tò, kò ní yàgò fún klkẹ́, kò ní í fi ọ̀nà sílẹ̀ fún alùpùpì, a wí pé kí aráyé má baà fi òun ṣe yẹ̀yẹ̀, a máa rìn lójú ọ̀nà rélùwé, a dúró sí ojú ọ̀nà de gẹdú, á sì máa fi ejò olóró ṣiré, bẹ́ẹ̀ ni kò ṣọ́ra pẹ̀lú àkeekèé, ó ń rìn kiri ní ọ̀gànjọ́ òru, ó ń káàkíri láàrin ẹ̀fúùfù, bí ó si tílẹ̀ jẹ́ pé kò mọ̀ ìwẹ̀, síbẹ̀ a máa siré ní ibi omi jíjìn, a máa jẹ ìjẹkújẹ káà kiri òde, a máa mu ìmukúmu káà kiri ilé onílé, a sì máa hu onírúurú ìwà àfara káàkiri orí ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, olúwaarẹ̀ ń dán Ọlọ̀run Ọba wò, ó ń fi Olódùmarè ṣe yẹ̀yẹ́, ó ń pèsò sílẹ̀ de ọjọ́ ìparrun. Nítorí eléyìí ńkọ́, nígbà tí ó di ọjọ́ kan báyìí, nítorí ọkùnrin náà kò wo iwájú, mọ́tò ńlá kan kọlù ú, ó ṣubú lulẹ̀, ọkàn rẹ̀ kò sì lù kìkì mọ́, bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè ti pa á láṣẹ fún mi pé, ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò bá lù kìkì mọ́, kí n mú olúwaarẹ̀ wá síwájú òun. Bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí pa ojú dé, tí ó kí ayépé ó dìgbòóṣe. Èyí ẹ̀kẹta jẹ́ ońwàpẹ̀lẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n baba tíó bí baba rẹ̀ burú ju májèlé lọ, bẹ́ẹ̀ ni Ẹlẹ́dàá tí ṣe ìlérí náà pé, òun kò nì ṣàìbẹ ẹ̀sẹ̀ baba wò lára ọmọ títí dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin nítorí ẹni tí ó bá ń hùwà tí ó fẹ́, ọmọ olúwaarẹ̀ ń bọ̀ wáá jèrè ìwà náà lẹ́hìn ọ̀la. Nígbà tí Olódùmarè sì rántí ẹ̀sẹ̀ ńlá tí baba ńlá ọkùnrin yìí ṣẹ̀ Ó rán mi kí n lọ mu un wá. Èyí ẹ̀kẹrin je arẹwà obìnrin nínú ayé ṣùgbọ́n àggàbàgebè ènìyàn ni, nígbà tí ó wà ní wúndíá, ó ń ṣe ìlara àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀, ó ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin àwọn ọ̀rẹ́ méjì, àwọn ọkùnrin méje ni wọ́n wí pé kí ó fẹ́ àwọn ó sì gbà láti fẹ́ àwọn méjèèje, bẹ́ẹ̀ àsẹ̀hìnwá-àsẹ̀hìnbọ̀ kò fẹ́ enì kan ṣoṣo nínú wọn mọ́. Nígbẹ̀hìn ọ̀rọ̀ yìí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọn-ọnnì ṣe é ní ibi, ó lo òògùn burúkú fún un ẹ̀jẹ̀ ara obìnrin náà kò sì ṣàn mọ́, nígbà tí ọkàn rẹ̀ kò lù kìkì mọ́, mo lọ ṣe iṣẹ́ tí Olódùmarè rán mi, mo mú ẹ̀mí rẹ̀ jáde, ìbànújẹ́ sì pọ̀ ní agbo-ilé náà gidigidi. Èyí ẹ̀karùn-ún ni ó fi àìka nǹkan sí bá ayé ara rrẹ̀ jẹ́. Ẹsẹ̀ lásán ló fi kọ, ṣùgbọ́n nítorí kò ka ẹsẹ̀ náà sí, ẹsẹ̀ di egbò, kò tètè san mọ́ kòkòrò búburú sí bá ibẹ̀ wọlé. Lẹ́hìn tí ẹsẹ̀ yìí san tán kòkòrò jókòó sí inú ara lọ́hùn-un ó fi ibẹ̀ ṣe ilé, ní ìgbẹ̀hìn, oríṣiríṣi àìsàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ọkùnrin yìí, àìsàn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí fa òmíràn jáde ṣùgbọ́n kòkòrò ìjọ́sí ni ó bẹ̀rẹ̀ nǹkan wọ̀nyí. Àsẹ̀hìnwwá-àsẹ̀hìnbọ onírúurú àwọn kòkòrò wọn-ọnnì lọo sí agbárí ọkùnrin náà, orí rrẹ̀ sì yí, ó di asínwín, ó kó àkísà bọ ọrùn, ó ń rin ìhòhò láti ìlkú dé ìl’, irun orí rẹ̀ kún ó sì ń pupa bí ara ewéko ojú ọ̀nà mọ́tọ̀, ó ń sùn nínú òtútù láàrin òde, ó ń jẹ́ àjẹkù àwọn ènìyàn káà kiri ilé, àwọn ọmọdé sí ń sọ òkò lù ú bí ó bá tí ń rìn lọ. Inú ìwọ̀nyí ni àìsàn dé bá a, nígbà tí ó sì pẹ́ àìsàn náà ṣe é dé ibi tí ọkàn rẹ̀ kò fi lù kìkì mọ́, èmi náà sì lọ mo mú un tọ Ẹlẹ́dàá mi lọ. ‘Èyí ẹ̀kẹfà jẹ́ oníwàrere nínú àwọn ọmọ ènìyàn ṣùgbọ́n bíi ó bá pẹ́ nínú ayé sí i ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyà ni ìbá jẹ́ ẹ́ nítorí àìsàn ńlá kan ìbá ṣe é kò bá sì tí sí oníṣègùn tí ó lè wò ó sàn bẹ́ẹ̀ ní àìsàn yìí kò bá tètè pa á, ìbá fi ìyà jẹ ẹ́ títí kí n tóó lọ mú un. Bí àìsàn yìí kòbá dé sí ọkùnrin náà ìjà ńlá kan ìbá bbẹ́ sílẹ̀ tí orílẹ̀-èdè yóó fi máa dìde sí orílẹ̀-èdè, tí ìjọba kan yóò fi máa dìde sí ìjọba kejì bẹ́ẹ̀ ni orí ọkùnrin yìí ní ìjà ìbá ti bẹ̀rẹ̀, orúkọ rẹ�� ìbá sì bàjẹ́ láti ìrandíran. Nítorí ìwọ̀nyí ni Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún mi kí n lọ mú un wá síwájú Òun. Ènìyàn lásán ni ẹnì keje, kò sí nínú àwọn alátùn-únṣe inú ayé, oníbàjẹ́ ènìyàn ni. Ó fi ìwà àgàbàgedè dé ipò gíga, ó dé ipò gíga tán kò jẹ́ kí ọwọ́ àwọn èrò ẹ̀hìn gòkè, bẹ́ẹ̀ ni ìrìra ni ó jẹ́ níwájú Olódùmarè ìwà ẹ̀gbin sì ni níwájú àwọn ẹ̀dá ọ̀run, wí pé, kí ẹni tí ó dé ibi gíga máa wá ọ̀nà ìdíwọ́ fún àwọn tí ń bọ̀ lẹ́hìn, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin náà gbàgbé ará ayé, ó gbàgbé ará ọ̀run, ó sì tún gbàgbé Ọlọ́run Ọba. Ìwà burúkú ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ ìwà wọ̀bìà ń be ní oókan-àyà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ nni ọmọ òkùnkùn ni òun í ṣe. Ọkùnrin yìi kún fún àbẹ̀tẹ̀lẹ̀òun ni alága ẹgbẹ́ ríkísí, òuun ni olórí àwọn alarèékérekè, òun ni balógun àwọn tí ń yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ káà kiri òde òru. Ó ti fi ẹnu ba iṣẹ́ oníṣẹ́ jẹ́, ó ti fi àpáàdì ńlá bo iṣẹ́ rere ẹlòmíràn mọlẹ̀, kí aráyé má baà rì iṣẹ́ rere wọn, bẹ́ẹ̀ ni a máa wá ibi kọ́lọ́fin kiri láti mú ọmọnìkejjì, rẹ̀, a sì máa sọ àṣìẹ kékeré wọn di títtóbi lójú àwọn ọmọ aráyé. Ẹni tí ó mú ayé doríkodò, tí ó gbé elékèé gorí ìtẹ́, tí óo fi olódodo sí ibi ìsàlẹ̀, nítorí ẹni ilẹ̀ ni òun í ṣe, kò lè bá ará òkè ṣe dọ́gbadọ́gba tító láéláé. Nígbà tí ọkùnrin yìí wà ní òdé ayé èdè Ẹlẹ́dàá kò yẹ àwọn ọmọ ènìyàn, nítorí Ọlọ́run fún un ní owó, Ó fún un ní ọmọ, Ó sì fún un ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣúra inú ayé. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn nǹkan wọn-ọnnì kò lè pẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, òun ní wọn kí ìwólulẹ̀ rẹ̀ baà lè pọ̀ gidigidi. Nígbà tí ó dé ṣóńṣó ìgbéga rẹ̀ tán, Olódùmarè rẹ̀ ẹ̀ sílẹ̀, ó ṣubú, ó di èrò ẹ̀hìn, ìbànújẹ́ dé bá a, ọkàn rẹ̀ kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì, orúkọ rẹ̀ sì burú tóbẹ́ẹ̀ nínú ayé tí àwọn ènìyàn kò jẹ́ fi orúkọ náà sọ ọmọ wọn. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Ẹlẹ́dàá mi ní kí n lọ mu un wá, kí àwọn aráyé baà lè mọ̀ pé kò sí àìṣòdodo lọ́wọ́ Olódùmarè, olúkulùkù kò ní ṣàìjèrè iṣẹ́ rẹ̀, yálà ní òde ayé, tàbí ní òde ọ̀run. Kíyèsí i ìwọ rí ìyyà tíóń jẹ ọkùnrin náà nínú ilé mi, má ṣe rò pé ìkàni a ń ṣe sí i nì, nítorí nígbà tí ọkùnrin yìí wà ní òde ayé, tí ó wà ní ipò giga, ó ti pàṣẹ kí wọ́n bẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lórí, kí wọ́n ṣá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lọ́gbẹ́, kí wọ́n fi ìyà búburú jẹ ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ènìyàn láìníddìí. Rántí wí pé Olódùmarè fẹ́ràn àwọn ọmọ ènìyàn púpọ̀-púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí Ó fi ohun gbogbo tí ń bẹ lóde ayé, bí ayé ti kún fún oríṣiríṣi nǹkan tó wọn-ọnnì, Ó fi àwọn nǹkan wọn-ọnnì jìǹkí ọmọ ará ayyé. Ọkùnrin tí ìwọ ń wò yìí ti fi ìyà jẹ àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run fẹ́ràn, tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ náà kò ṣeé fi ẹnu sọ! Ohun tí olúkúlùkù bá gbìn ni yóó hù jáde fún un. N kò fẹ́ kí n sọ̀rọ̀ púpọ̀ jù nísisìyí, ìwọ ọmọ ènìyàn, mo kí ọ, o kú àbọ̀, mi sì kí ọ̀rẹ́ mi náà pé ó kú àléjò, ọ̀gbẹ́ni pàtàkì, Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́, ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta. Báyìí ni ẹbọra ńlá náà sọ̀rọ̀ fún wa, Ikú, ẹ̀dá tíkò ní ìtìjú ẹnikẹ́ni, tí kò jẹ̀ wí pé ènìyàn ńlá ni èyí òun kò ní í mú un lọ, ẹni tí ilẹ̀ rẹ̀ ń bẹ lagbedeméjì ayé òun ọ̀run. Kí ó tóó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ọkàn mi ti balẹ̀ díẹ̀ mo sì pinnu àti sọ̀rọ̀ rere fún un kí n baà lè rí ọ̀nà jáde. Mo dáhùn, mo wí pé: Ìwọ ẹbọra pàtàkí, Ikú, ẹni tí ilé rẹ̀ ń bẹ lágbedeméjì ayé òun ọ̀run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ. A fún ọ láṣẹ lórí ohnu gbogbo nínú ayé, lórí ohun alààyè gbogbo. A fún ọ láṣẹ lórí ọba àri àwọn ọmọ aládé, lórí olówó àti tálákà, lórí oníṣègùn àti lórí adáhunṣe. Ìwọ lágbára lórí ẹranko ìgbẹ́ àti lórí ejò afàyàfà, kìnnìún àti ìmàdò, ìkòokò àti àjànàkú, òjòlá àti àwọn ejò gbogbo. Ìwọ lágbára lórí ẹyẹ ojú ọ̀run àti lórí ẹja inú òkun, lórí eweko orí ilẹ̀ àti lórí àwọn kòkòrò kéékèèkéé. Àwọn jagunjagun tí ó ti kọjá ìwọ lo mú wọn lọ, àwọn tí ń sọ̀rọ̀ tí ọ̀rọ̀ náà ń múlẹ̀ ìwọ tí mú wọn kúrò lórí ilẹ̀, àwọn ènìyàn pàtàkì nínú ẹgbẹ́ àti àwọn ìjòyè nínú igbìmọ̀ ni ìwọ ti fẹ́ ojú wọn kù, inú mi sì dùn lónìí, tí mo mọ ẹ̀dá tí ó tóbi bí ìwọ. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó sọ n ó sì jíṣẹ́ rẹ fún àwọn ọmọ aráyé, n kò ní í fi ọ̀kan pe méjì, nítorí máà mo fẹ́ kí o yọ̀ọ̀da fún mi lónìí n óò tún padà wáá rí ọ lọ́la, nǹkan kan ni mo ń ṣe lọ́wọ́ tí mo fi sílẹ̀ tí mo ní kí ń yára wáá fi ojú gán-ánnní rẹ, nítorí náà ó dìgbà díẹ̀ nísisìyí ná, mo ń lọ sí ilé, lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ mi. Ọkùnrin mẹ́ta, Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́, ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta.’ Nígbà tí mo parí ọ̀rọ̀ tèmi, èmi àti Ikú kí ara wwa, a kò bọ ara wa lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ nì ẹni kan kò sì dọ̀bálẹ̀ fún ẹnì kejì ṣùgbọ́n dípò wọn-ọnnì, a mi orí sí ara wa, lẹ́hìn náà a sì kí ara wa ó dìgbòóṣe, kí Ọlọ́run jẹ́ kí á fi ire pàdé lọ́la. Bẹ́ẹ̀ ni èmí àti ọ̀rẹ́ mi kúrò nínú ilé ẹ̀mí burúkú náà tí a bá ilé tiwa lọ, nígbà tí a sì ń bọ̀ lọ́nà tí mo béèrè ìdí rẹ̀ tí Baba-onírùngbọ̀n fi ń ṣẹ́jú sími wípé kí n má bọ Ikú lọ́wọ́, kí n má sì ṣe dọ̀bálẹ̀ fún ẹbọra náà, àti wí pé n sọ́ra lórí àkete rẹ̀, ó dá mi lóhùn, ó wí pé: Ẹni tí ó bá bọ Ikú lọ́wọ́ tí olúwaarẹ̀ parí, ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀ fùn un ti olúwaarẹ̀ sọnù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá jókòó lórí akéte rẹ̀ ti olúwaarẹ̀ di ọ̀run alákeji.’ Nígbà tí Baba-onírùngbọ̀n sọ̀rọ̀ yìí, ọ̀rọ̀ náà jọ mí lójú, ẹ̀rù sì túbọ̀ bà mí, gbogbo nǹkan burúkú ilé ẹ̀dá náà sì ń sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí odò inú mi. Èmi tí mo ní ìyàwó tí a kò í tí ì jọ gbé pọ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ rí, n kò ì tíì jọ gbé pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ rí, n kò ì tíì fẹ́ kí tèmi parí nínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni èmi tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ pé mo bímọ tí n kò ì tí ì rí ọmọ náà, n kò ì tí ì fẹ́ kí témi sọnù, èmi tí ó sì ti ń jìyà káàkiri inú ayé, tí n kò ì tí ì gbádùn ayé náà rí, n kò ì tí ì fẹ́ẹ́ múra ọ̀run alákeji. Mo wi fún ọ̀rẹ́ mi wí pé: Ìwọ ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, bí o bá tún rí ẹsẹ̀ mi ní ilé aládùúgbò rẹ̀ yìí mọ̀, wí pé bàbá mi kọ́ ló bí mi. Baba-onírùngbọ̀n náà sì dá mi lóhùn, ó ní, ‘Bí ó ti wù kí ó sí ṣáá mo rò pé o kò ní ṣàìdé ibẹ̀ lọ́la, nítorí pé ó ti ṣe ìlérí fún un ó sì yẹ kí o mú ìlérí rẹ ṣẹ. Ó fẹ́rẹ̀ má ì tí ì parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yií nígbà tí èmi náà ti fún un lésì, mo ní, N kò ní í mú ìlérí eléyìí ṣẹ. Nígbà tí mo wí báyìí tán, Baba-onírùngbọ̀n rẹ́rìn-ín, ó ní, Ọ̀rẹ́ mi, mo ṣe bí ìwọ lo ń ṣe ìlérí níwájú ọk[]unrin náà nísisìyí tí ẹnu rẹ ń lekoko? Èmi náà sì tún fèsì, mo ní, ‘Hin-in, bí ẹnu mi bá ń le koko ńkọ́? O’ju bọ̀rọ̀ la fi ń gba ọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́ ńdan? Ìwọ rí ojú ọkùnrin náà ó dà bí iná, ìwọ rí èékán rẹ̀ ó dà bí èékán ẹkùn, ìwọ wáá tún ń béèrè pé kí n sọ̀rọ̀ rere tàbí kí n má sọ̀rọ̀ rere, o kò mọ̀ pé bí mo fẹ́ bí mo kọ̀ mo níláti sọ nǹkan rere níwájú ọkùnrin náà ńdan? Baba-onírùngbọ̀n sì tún dáhùn, ó ní, Họ́wù o, kò mà dára o, kò yẹ kí á ṣè ‘lérí kí á máà mú ‘lèérí wa ṣẹ o, ó yẹ kí á lọ dé ilé ọkùnrin náà lọ́la o. Lẹ́hìn tí ó wí báyìí tán, mmo kígbe ńlá, mo ni, ‘Dé ilé ta ni? – Baba-onírùgbọ̀n, dé ilé ta ni sẹ́ẹ̀?’ Òun náà sì tún fésí, ó ní ‘De ilé tani ìbá tún ṣe? – Ilé Ikú kọ́!’ Inú wáá bí mi, mo ní, ‘Orí rẹ ni yóò dé ilé Ikú, àyà rẹ ni yóò dé ilé Ikú, ìwọ abi ‘rùngbọ̀n yẹ̀ùkẹ̀yẹukẹ yìí.’ Nígbà tí mo wí báyìí tán, Baba-onírùgbọ̀n náà tún fún mi lésì, ó ní, ‘Rùngbọ̀n mi rí yẹ̀ùkẹ̀ o, kò rí yẹ̀ùkẹ̀ o, a óò dé ilé ọkùnrin náà lọ́la dandan. Bí o fẹ́ bí o kọ̀ n ó fà ọ́ dé ‘bẹ̀ bí ó ṣe gbígbé ni n óò gbé ọ. Nígbà tí ọkùnrin náà tún wí báyìí inú túbọ̀ bí mi, mo ní, Baba-onírùngbọ̀n n kò mà fẹ́ o. Ẹ kò rí ‘rùngbọ̀n rẹ̀ bí ó ti ń gbálẹ̀ guruguru.’ Ṣùgbọ́n dípò kí òun bínú ó tún fún mi lésì, ‘Mo ṣe bí ìwọ ń fi ọwọ́ tẹ ìbàdí nígbà náà ni? Jẹ́ kí n sọ fún ọ, mo ti ń pérò nínú ara mi nísisìyí láti se àsè ńlá kan láti fi ṣe àjọyọ̀ nítorí rẹ, kí n sì pe àwọn ẹbọra Igbó Olódùmarè sì ibi àsè náà, mo sì tànmọ́ọ̀ lọ́k��n mi láti fi ikú jẹ alága, àti láti fi àrùn jẹ igbá kejì rẹ̀, kí n sì fi ìwọ sí ipò ẹni í ń ṣe ọdún láàrin wọn.’ Nígbà tí ó wí báyìí tàn ẹ̀rù bà mí, mo ní, mo sún mo kan ògiri ná wàyí, mo gbé ẹbọ kọjá mọ́ṣáláṣí, mo fi ẹlẹ́dẹ̀ jẹ sàrì, mo sun ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú fún Òyìnbó jẹ, mo ní kí Haúsá kọ górò sílẹ̀, mo wí pé Yorùbá kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀kọ - Ọ̀rọ̀ yìí bí mi nínú tóbẹ́ẹ̀ tí n kò fi sọ̀rọ̀ sí Baba-onírùngbọ̀n-yẹ̀úkẹ́ títí a fi dé ilé. Nígbà tí a dé ilé mo pinnú láti bẹ̀ ẹ́ mo sì bẹ̀ ẹ́ dára-dára, mo wí pé n kò ní í lè padà dé ilé Ikú mọ́ àri pé kí ó jọ̀wọ́ bá mi ṣe ọ̀nà rẹ̀ tí n kò ní í fi tún padà lọ mọ́. Lẹ́hìn èyí, Baba-onírùngbọ̀n fi èsì fún mi, èsì rẹ̀ náà sì kún fún mi, èsì rẹ̀ náà sì kún fún ọgbọ́n gidigidi. Ó dáhùn, ó sí wí pé: ‘Olówó-ayé, nǹkan kan wà tí mo fẹ́ẹ́ sọ fún ọ lónìí, mo fẹ́ ki’o ṣe àkíyèesí nǹkan náà kí o sì fi ṣe àríkọ́gbọ́n. Bí o bá rí ènìyàn kan tí ó ṣe ìlérí tí kò mó un ṣẹ mo fẹ́ kí o mọ̀ dájú pé olúwaarẹ̀ kò ṣeé gbẹ́kẹ̀lé. Bí ọmọlúwàbí bá sọ̀rọ̀ ó yẹ kí ènìyàn bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀, ìlérí ọmọlúwàbí dà bí ẹ̀wọ̀n tí òun fi de ara rẹ̀, láìjẹ́ pé ó bá sì ṣe bí ìlérí náà ẹ̀wọ̀n náà kò ì tí ì tú; ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ka ìlérí sí nǹkan eré, bí òun bá sọ eléyìí lónìí a sọ tọ̀hún lọ́la, gbogbo arayé a sì máa ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ènìyàn yẹpẹrẹ tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ọ̀rọ̀ tí ó lè sọ tí ọmọ aráyé kò ní í kà sí yẹ̀yẹ́. Olówó-ayé, ọmọlúwàbí ni ọ́, bí ó sì ti wù tí ọ̀ràn náà burú tó mo fẹ́ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nǹkan tí mo lè ṣe ni eléyìí, n kò ní í pe Ikú kí ó wáá bá mi jẹ àsè nítorí rẹ mọ́, nígbà tí a bá sì dé ilé ẹbọra náà lọ́la, a ko ní í wọlé, dípò èyínì a óò dúró sí òde a óò wí pé a ń lọ sí ibi kan ni á wí pé kí á yà gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí a ṣe fún un. Nígbà tí ọkùnrin náà parí ọ̀rọ̀ yìí mo tún èrò mi pa; nítorí mo rí i pé ọ̀rọ̀ náà ti bọ́ sí orí àfi bí mo bá ń múra de ọjọ́ kejì, bí mo fẹ́ bí mo kọ̀ mo nílatí tún fi orí mi lé ọ̀nà ilé Ikú, ẹni tí ilé rẹ̀ ń bẹ lágbedeméjì ayé òun ọ̀run. ỌJỌ́ KẸTA LỌ̀DỌ̀ BABA-ONÍRÙNGBỌ̀N-YẸ́ÚKẸ́ Ẹ́NI TÍ Ń GBÉ IBI GEGELE ÒKÚTA N kò sùn mọ́jú ọjọ́ kejì, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tí mo si pa ojú dé, àlá burúkú ni mo lá, ṣe ni mo rí ẹbọra burúkú kan lójú àlá tí ó bẹ̀rẹ̀ sí lé mì kiri, ibi tí ẹbọra náà ti ń lé mi lọ ni mo ti pàdé ejò kan lójú ọ̀nà eyín rẹ̀ dàbí kìnnìún, ìgbà tí mo sì tún ní kí ń sa fún eléyìínì mo pàdé ẹranko tí kò sanra, tí ó dàbí olókùnrùn ti èékan rẹ̀ gùn ṣọ̀bọ̀lọ̀, eléyìínì tún ń fẹ ojú mọ́ mi. Lẹ́hìn èyí, mo jí. Nígbà tí mo jí ṣe ni mo ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ẹni tí ń sáré ije tí ọkàn mi ń lù kìkì bí ọkọ̀ òfuurufú – Háà! Ojú mi rí nǹkan nínú Igbó Olódùmarè, ojú mi rí nǹkan. Nígbà tí mo jẹun òórọ̀ tán lọ́dọ̀ Baba-onírùngbọ̀n lọ́jọ́ kejì yìí mo wí fún un kí ó jẹ́ kí á lọ sí ilé Ikú kí á tóó dáwọ lé ohunkóhun ní ṣíṣe òun náà sì gbà sí mi lẹ́nu. Nígbà tí a dé ọ̀hún a kò bá ẹbọra náà ní ilé ṣùgbọ́n a ránńṣẹ sílẹ́ dè é wí pé bí ó bá padà dé ilé ki wọ́n jíṣẹ́ wa fún un. Bẹ́ẹ̀ ni mo padà tayọ̀tayọ̀ tí mo wá sí ilé ọ̀rẹ́ mi, lọ́dọ̀ Baba-onírúngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta. Ọ̀rẹ́ mi yìí ṣe mi ní àlejò púpọ̀ kò sì jẹ́ kì ń fi ẹnu mi kàn àkàrà tí ìyá mi mú wá fún mi láti ìsálú ọ̀run. Nígbà tí a padà ti ilé Ikú dé tí a tún jẹun lẹ́ẹ̀kejì, Baba-onírùngbọ̀n mú mi gun òkè peẹ̀tẹ́eẹ̀sì rẹ̀ lọ, nígbà tí a sì dé ọ̀hún tàn tí ó jókòó tí èmi náà jókòó tí a kọjú sí ara wa tán ó wí fún mi pé nǹkan pàtàkì tí a ó ṣe lọ́jọ́ náà kò ju ọ̀rọ̀ tí òun óò bá mi sọ. Nígbà tí ó sì sọ èyí fún mi tán, inú èmi náà dùn, mo jókòó dáadáa mo wí fún ọ̀rẹ́ mi tuntun yìí pé mo tẹ́tí sílẹ̀, kí ó máa bá ọ̀rọ̀ lọ. Ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó wípé: Láì-ṣe-àní-àní, kò ní ṣáìyà ọ́ lẹ́nu bí o ti ṣe déédéé bá mi nínú igbó yìí nígbà tí o dé ọ̀dọ̀ mi ní ìjẹta. Irú ẹni tí mo jẹ́ kò lè yé ọ bẹ́ẹ̀ ni ó kò sì lè mọ irú ipò tí mo wà láìjẹ́ pé mo bá sọ ìwọ̀nyí fún ọ. Èmi tí ìwọ ń wó yìí jẹ́ apá kan ènìyàn àti apá kan iwin. Nítorí kí ni ńkọ́? – Nítorí ènìyàn ni bàbá mi, ọdẹ ni òun si í ṣe pẹ̀lú, lákòókò igbà tí mo ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, ọjọ́ pẹ́, ṣùgbọ́n bàbá mi ló gbójú jù nínú gbogbo àwọn ọdẹ inú ayé lákòókò tí wọ́n bí mi. Ìyá mi kì í ṣe ènìyàn rárá, iwin ni. Ṣùgbọ́n ìyá mi lẹ́wà gidigidi. Gẹ́gẹ́ bí àṣà púpọ̀ nínú àwọn arẹwà obìnrin, ìyá mi jẹ́ onígbèéraga, àwọn iwin pàtàkì pàtàkì ti wọ́n sì ń fẹ́ ẹ nígbà tí òun wà ní wúndíá kò bá ojúrere rẹ̀ pàdé títí àwọn ọlọ́lá wọn-ọnnì fi fi í sílẹ̀ tí àti ní ọkọ di ìṣòro fún un. Àsẹ̀hìnwwá-àsẹ̀hinbọ̀, bàbá mi rí i nínú igbó ó sì fẹ́ ọ, gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ti lọ, bàbá mi ti gbúròó ẹbọra náà rí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá a kiri. Ní ayé ìgbàànì àwọn obìnrin gbọ́ ju ti ayé ìwòyí lọ, nítorí wọn kì í fẹ́ ọkùnrin nítorí fáàrí ọkùnrin, wọn kì í fẹ́ ẹ nítorí ẹwà rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n wọn a máa fẹ́ ẹ bí ó bá jẹ́ alágbára ọkùnrin, bí ó bá ní ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ tí ko lè ṣá, bí ó bá sí mọ nǹkan títọ́ ní àti nǹkan yíyẹ ní yiyẹ. Nítorí bí ènìyàn bá mọ nǹkan títọ́ ní títọ́ àti nǹkan yíyẹ ní yíyẹ a kò ni í bá olúwaarẹ̀ ní ìdí nǹkan tí kò yẹ ọmọ ènìyàn. Nítorí náà lákòókò yìí, ìyá mi mú bàbá mi lọ sí inú òkúta ní ilé wọn wọ́n sí dán an wò. Níbẹ̀ bàbá mi bá kìnnìún jà ó fi àáké pa kìnnìún, bàbá mi bá ẹkùn jà ó fi kùmọ̀ pa ẹkùn, bàbá mi bá òjòlá jà ó fi pàṣán pa òjòlá, ọjọ́ méje ni òun si gbà ní àìjẹun. Nígbà tí bàbá mi parí eléyìí obìnrin náà wwáá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó ní, Kí ni ìdí rẹ̀ tí ìwọ fi fẹ́ràn mi? Bàbá mi náà sì fèsì ọlọgbọ́, ó ní, Mo fẹ́ràn rẹ ṣùgbọ́n ìdí ìfẹ́ náà kò yé èmi pàápàá, bí mo bá ti ń ríi ọ mo sáà ń fẹ́ràn rẹ ni. Obìnrin náà dáhùn, ó ní, N óò fẹ́ ọ ìwọ ọlọgbọ́n ọkùnrin nítorí ìfẹ́ tí ó pé jùlọ ni ìfẹ́ tí ènìyàn kò lè sọ ìdí rẹ̀, bí ènìyàn bá fẹ́ràn ẹnì kan nítorí ojú rẹ̀ dára, bí ó fẹ́ ẹ nítorí ipò tí olúwaarẹ̀ ní, bí ó fẹ́ ẹ níttorí ìdílé rẹ̀ tí ó dára, bí ó fẹ́ ẹ nítorí ọgbọ́n orí rẹ̀, bí ó fẹ́ ẹ nítorí fáàrí rẹ̀, bí ó fẹ́ ẹ nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀, bí ó bá sì fẹ́ ẹ nítorí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀, ìfẹ́ náà kò jámọ́ nǹkan kan. Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ tí àwọn nǹkan wwọ̀nyí le ṣe aláìsí mọ́ tàbí tí wọ́n lè sú ọ; ṣùgbọ́n bí o bá fẹ́ ènìyàn tí ìwọ kò sì lè sọ nǹkan kan pàtó tí o fi wù ọ́, ìfẹ́ pípẹ́ ni ìfẹ́ rẹ. Nítorí náà, mo máa fẹ́ ọ, ìwọ́ ni yóó sì ṣe baálé mi. Ìwọ́ ọ̀rẹ́ mi, báyìí ni bàbá mi ṣe tí ó fi fẹ́ ìyá mi, lákòókò tí wọ́n sì fi bími, ìyá mi, níwọ̀n ìgbá tí òun náà ti jẹ́ iwin, ó rọra yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ síìsálú ọ̀run óo já ọ̀kan nínú àwọn èèso igi ìyè ó fi í fún mi mo sì jẹ́ ẹ́ bẹ́ẹ̀ ni n kò lè kú títí ayé mọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọlọ́run Ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, Ó pa á láṣẹ fún àwọn màlékà pé bí mo bá tí gbé ààrin àwọn ọmọ ènìyàn fún àádọ́rin ọdún kí wọ́n mú mi wá sí etí bodè ọ̀run. Ìdí rẹ̀ sì ni èyí tí ìwọ fí bá mi ní ìhìn níbi tí mo ti ń gbọ́ àkúkọ ọ̀run – èmi náà, Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́, ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta. Ṣùgbọ́n ìwọ ọ̀rẹ́ mi, nígbà tí mo wà ní ààrin àwọn ọmọ ènìyàn, mo rí púpọ̀ nínú àṣírí wọn. Ìwọ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa ọ̀kan nínú àwọn ìwà buburú tí wọ́n máa ń hù, jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ nípa ilara wọn. Èmi ni mo wí fún ọ, bí ayé yípadà tó bẹ́ẹ̀ tí àgùntàn ń lóyún ewúrẹ́ tí ológbò sì ń lóyún àkùkọ inú onílara kò ní í dùn láéláé. Onílara kì í fẹ́ kí ẹlòmíràn lọ síwájú àfi òun; onílara kì í fẹ́ kí ẹlòmíràn mọ ìwé àfi òun; onílara kì í fẹ́ kí ẹlòmíràn dé ipò ńlá àfi òun; onílara kì í fẹ́ kí ẹlòmíràn kọ́ ilé àfi òun; onílara kì í fẹ́ kí ẹlòmíràn ní ọmọ tí ó níláárí àfi òun – bẹ́ẹ̀ ni ayé kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn a kò si lè ṣe aláìrì àwọn tí yóó maa lọ síwájú lọ́nà wọ̀nyí bẹ́ẹ̀ ni bíi wọ́n bá ti ń lọ síwájú ni inú onílara yóó máa bàjẹ́, nítorí náà inú onílara kò lè dùn láé, bí ayé yípadà tí ó di ọ̀run. Fetí sìlẹ̀ kí n sọ ìtàn kékeré kan fún ọ. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí mo fi wà láàrin àwọn ọmọ ènìyàn, ọkùnrin kan wà lẹ́bàá ilé wa. Ọkùnrin náà tálákà púpọ̀ ó sí ní ìyàwó kan. Ìyàwó yìí fẹ́ràn ọkọ rẹ̀ púpọ̀, títí wọ́n sì fi wà nínú ìpọ̀njú yìí kò fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́jọ́ kan. Nígbà tì ó ṣe, ọkùnrin olówó kan pinnu láti ran tálákà yìí lọ́wọ́. Olówó náà ní ilẹ̀ kan tí kún fún igi ọ̀pẹ. Ó pe ọkùnrin yìí ó sì bá a ṣe ètò wí pé kí ó máa dá ẹmu lórí ọ̀pẹ wọ̀nyí, nígbà tì í bá dá ẹmu náà tán tí ó tà á, kí àwọn jọ máa pín owó tí ó bá ti ibẹ̀ jáde ní dọ́gbadọ́gba. Ó fún tálákà yìí ní owó tí yóó fi ra akèǹgbè àti gbogbo nǹkan fífí dá ẹmu. Inú ọkùnrin yìí dùn ó sì múra lọ́jọ́ kan ó lọ sí oko náà ó dá ẹmu ó sì so àwọn akèǹgbè wọn-ọnnì mọ́ orí ọ̀pẹ nírètí pé nígbà tí ó bá di ọjọ́ kejì tí òun bá dé òun óò bá ẹmu nínú àwọn àkèǹgbè wọn-ọnnì òun óo sì tà á, òun àti olówó náà yóó jọ pín owó tí ó bá ti ibẹ̀ wá ní dọ́gbadọ́gba. Nígbà tí ó di ọjọ́ kejì tí ọkùnrin yìí lọ sí ibi ọ̀pẹ wọn-ọnnì ó bá àwọn akèǹgbè tí ó ti so mọ́ ọ̀pẹ ní ilẹ̀ ní fífọ́. Eléyìí yà á lẹ́nu lọ́pọlọpọ̀ ó sì dùn ún gidigidi. Nígbà tí ó padà dé ilé ó mú owo díẹ̀ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ ó fi ra àwọn akèǹgbè mìíràn ó lọ so wọ́n mọ́ orí ọ̀pẹ ṣùgbọ́n nígbà tí ó tún dé ibẹ̀ lọ́jọ́ kejì ó bá àwọn akèǹgbè wọn-ọnnì ní ilẹ̀, wọ́n ti fọ́. Ọkùnrin yìí tún wá ọ̀nà míràn ó rí owó ó tún ra àwọn akèǹgbè míràn ó sì pinnu láti rí nǹkan tí ó ń fọ́ akèǹgbè òun, nígbà tí ó dá ẹmu tán kò lọ sì ilé, ó gun orí igi kan lọ ó ń wo nǹkan tí yóó ṣẹlẹ̀ sí àwọn akèǹgbè òun, ó dúró títí ilẹ fi ṣú kò rí nǹkan kan òun náà kò sì lọ. Nígbà tí ó di ààrin ọ̀gǹjọ́, ọkùnrin náà rí nǹkan kan tí ó ń bọ̀ ní ibi ọ̀pẹ wọ̀nyí ó sì wó ó dáradára. Ó rí i wí pé láti ẹsẹ̀ nǹkan náà sí ìsàlẹ̀ jẹ́ tí ènìyàn, ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ ti ènìyàn pẹ̀lú ṣùgbọ́n orí àti ara ìyókù jẹ́ ti àgbọ̀nrín pátápátá. Ìgbà tí abàmì ẹ̀dá yìí dé ibi ọ̀pẹ́ wọn-ọnnì ó bẹ̀rẹ̀ sí gún wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan ó ń gbé ẹmu orí wọn, ìgbà tí ó bá sì da ẹmu inú akèǹgbè orí ọ̀pẹ kan sí inú akèǹgbè ńlá tí ó gbé lọ́wọ́ tán, a ju akèǹgbè ti orí ọ̀pẹ sílẹ̀ eléyìínì a sì fọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ffọ́ àwọn akèǹgbè orí ọ̀pẹ wọn-ọnnì bí ó ti ń lọ láti ọ̀kan dé ọ̀kan. Ibi tì abàmì ẹ̀dá náà ti ń ṣe èyí ni ọkùnrin yìí ti kígba ńlá, igbì tí ó sì kigbe, ẹ̀dá yìí gbé akèǹgbè ẹmu ńlá tirẹ̀ ó ń sáré lọ. ọkùnrin náà sì ń tẹ̀lé e lọ. Òṣùpá dà bí ọ̀sán, wọ́n sáré títí ilẹ̀ fi mọ́ síbẹ̀ ọkùnrin náà kò padà ó ń lé e lọ ó sì lé e títí wọ́n fi dé ibi ẹsẹ̀ òkè kan, ọkùnrin yìí tún tẹ̀lé e, bí ó ti gun òkè yìí dé orí lọ́hùn-ún tán, ọkùnrin yìí bá ara rẹ̀ láàrin ońiruurú ẹranko gbogbo inú ayé yìí wọ́n wà nínú ìgbìmọ̀ wọn. Nígbà tí ó yọ sí ibẹ̀, abàmì ẹ̀dá náà ṣubú lulẹ̀ sí ààrin àwọn ẹranko wọ̀nyí ọkùnrin náà sì dúró pẹ̀lú ìbẹ̀rù láàárin wọn. Kìnnìún ọba ẹranko bínú gidigidi nítorí ìbànújẹ́ ní ó jẹ́ fún wọn láti rí ènìyàn tí í ṣe ọ̀tá ẹranko inú igbó láàrin wọn. Ọba yìí paa á láṣẹ pé kí wọ́n pa ọkùnrin náà. Ṣùgbọ́n bí ó ti pàṣẹ náà tán ni ọkùnrin yìí tọrọ gáfárà lọ́wọ́ àwọn ẹranko wọn-ọnnì wí pé wọ́n fún òun láyè kí òun sọ ti ẹnu òun, wọ́n sì gbà bẹ́ẹ̀ fún un. Ọkùnrin yìí wáá bẹ̀rẹ̀ mú ìtàn ó sọ bíòun ti ṣe jẹ́ tálákà tí olówó kan ṣàánú òun, àti bí òun àti olówó náà ti ṣe ètò nípa ẹmu àti bí òun ti ṣe bá akèǹgbè ẹmu òun ní fí fọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà kí ó tóó di pé òun pinnu àti wá nǹkan tí ó n fọ́ òun ní akèǹgbè ẹmu bẹ́ẹ̀, àti bí òun ti ṣe rí abàmì ẹ̀dé náà tí òun sì níláti lé e títí òun fi dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹranko. Nígbà tí ọkùnrin yìí parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ inú bí àwọn èranko púpọ̀ sí ẹ̀dá burúkú náà tí ó ń fọ ọkùnrin yìí ní akèǹgbè ẹmu. Àṣé àgbọnrín ni, àwọn ẹranko ni ó ń rán an kí ó lọ máa ra ẹmuu fún wọn níi àkókò ìpàdé, wọn a sì máa fún un ní owó ni, wí pé, kí ó tóó jáde sí ìlú kí ó sọ ara rẹ̀ di ènìyàn kí ó sì ra ẹmu, ṣùgbọ́n dípò kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ àgbọ̀nrín a fi owó sí àpò ara rẹ̀, a máa jí ẹmu ẹlẹ́muu káàkiri orí ọ̀pẹ a sì wáá máa sọ fún àwọn ẹranko pé rírà ni òun rà á. Nítorí èyí ẹsẹ̀ kan náà nì wọ́n pa àgbọ̀nrin olè tí ó ń gun orí ọ̀pẹ kiri. Àánú ọkùnrin yìí ṣe àwọn ẹranko wọn-ọnnì, nígbà tí wọ́n sí ronú ohun ti wọn ìbá ṣe fún un títí tí wọ́n kò mọ̀ ọ́n, wọ́n fún un ní agbára àti gbọ́ ohhùn àwọn ẹyẹ àti àwọn ẹranko bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ sí ara wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n pa á láṣẹ wí pé ọkùnrin náà kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun gbọ́ èdè ẹyẹ àti ti ẹranko àti pé ní ọjọ́ tí ó bá fi ìdí àṣírí náà han ọmọ ènìyàn ni yóò kú. Bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí padà wá sí ilé pẹ̀lú ẹ̀bùn ńlá yìí tí ó sì ń bá ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ lọ láì fi ìdí àṣírí náà han ẹnikẹ́ni. Nígbà tí ó di ọjọ kan báyìí, bí ó ti jókòó sí àgbàlá rẹ̀ tí ó ṣiré ní ìrọ̀lẹ́ ni ó gbọ́ tí àgbébọ̀ adìẹ̀ kan ń sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n ṣọ́ra kí wọ́n kúrò ní ibi kan báyìí, nítorí bí wọ́n bá dúró pẹ́ ní ibẹ̀ tí wọ́n ń tan ilẹ̀ ibẹ̀ wọn kò ní í pẹ́ rí àpò owó góòlù ní ìsàlẹ̀, àti pé ẹni tí ó ni ilé náà sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ rí i. Báyìí ni adìẹ̀ náà sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ láìmọ̀ pé ọwọ́ onílé ni òun sọ̀rọ̀ sì. Nígbà tí ó sì ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni àwọn ọmọ náà ti kúrò ní ibi tí wọ́n ti ń ṣiré, wọ́n tẹ̀lé ìyá wọn wọ́n ń wá oúnjẹ òójọ́ wọn lọ. Bái àwọn adíẹ̀ wọ̀nyí ti lọ tán ni ọkùnrin náà mú ọkọ́ tí ó mú àáké tí ó gbé àwọn ohun èlò tí ènìyàn lè fi wwa ilẹ̀ tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wa ilẹ̀ ibẹ̀ lọ. Láìpẹ́ ó kan àwọn àpò owó tí adíẹ̀ náà sọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn. Láti ọjọ́ náà wá ni àyípadà rere ti dé bá ọkùnrin yìí tí ó di olówó tí òkìkí rẹ̀ sì gba gbogbo àgbègbè kankan. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olówó ti máa ń ṣe, owó a máa ru bo ẹlòmíràn lójú bí omi òkun a sì máa pa ẹlòmíràn bí ẹmu, owó a máa mú kí àwọn ẹlòmíràn gbàgbé ibi tí àwọn tí dìde, dípò kí wọ́n sì máa fi owó wọn yin Ẹlẹ́dàá wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí tàpá sí ẹni tí ó dá wọn. Ọlọ́run lágbára, síbẹ̀ a kò ṣàìrí àwọn olóye lórí ènìyàn, tìi wọ́n lówó tí wọ́n tún ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ti wọ́n sì ń ba búrúbúrú níwájú Ọlọ̀run Ọba. Nígbà tí ọkùnrin yìí di olówó tán ó pinnu àti máa fẹ́ obìnrin lé orí obìnrin, ṣùgbọ́n ìyàwó tí ó kọ́ fẹ́ kò lẹ́wà, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì kò dára, arọ ni; ó fẹ obìnrin náà níttorí pé ọmọ ọba ní í ṣe bẹ́ẹ̀ ni ìlara obìnrin yìí ní ó pọ́ ju tí gbogbo obìnrin tí ńbẹ nínú ayé lọ. Obìnrin náà ti gbé ìlara wọ̀ bí ẹ̀wù; ó fi owú-jíjẹ sán yẹ̀rì, ó ró aṣọ wọ̀bìà sí ìbàdí, ó sì fi ìborùn ojùkòkòrò lékeè aṣọ. Láti ìgbà tí obìnrin náà ti wọlé kò tilẹ̀ fẹ́ kí ìyáálé rẹ̀ ní nǹkan kan pọ̀ pẹ̀lú ọkọ mọ́, kò fẹ́ kí ọkọ bá a sọ̀rọ̀, kò fẹ́ kí ọkọ bá a ṣiré, kò fẹ́ kí ọkọ ṣe nǹkan kan fún obìnrin náà mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ìyàwó yìí kò sí lọ́dọ̀ ọkọ nígbà tí onítọ̀hún kò ní aṣọ oókan. Nígbà tó ó di alẹ̀ ọjọ́ kan, ọkùnrin yìí àti ìyáálé náà wà nínú iyàrá, ìyàwó wà lóde, ibi tí wọ́n ti wà nínú iyàrá ni ọkùnrin náà ti ń gbọ́ tí àwọn èkúté méjì ń sọ̀rọ̀ sí ara wọn tí wọ́n ń bú ọkùnrin náà pé kò tètè sùn kí àwọn baà rí àyè lọ jẹun. Ibi tí àwọn èkúté náà ti ń sọ báyìí ọkùnrin náà bú si ẹ̀rin, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ́ má ì tí ì parí ẹ̀rín rẹ̀ tán tí ìyàwó burúkú yìí ti ta pẹẹrẹ wọlé tí ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe ńlá tí ó ń pariwo wí pé òun nni ọkùnrin yìífi ń ṣe yẹ̀yyẹ̀. Ọkùnrin yìí wí fún un pé kì í ṣe òun ṣùgbọ́n kòo gbọ́, ó ní àfi bí ó bá sọ nǹkan tí ó ń pa á lẹ́rìn-ín fún òun. Wọ́n ja ìjà yìí títí ilẹ̀ fi mọ́. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, obìnrin náà tọ bàbá rẹ̀ lọ ó sì sọ̀rọ̀ yyìí fún un. Ó purọ́ mọ́ ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú pé òun orúkọ òun níbi tí baalé òun àti ìyáálé náà ti ń sọ̀rọ̀ àti pẹ̀lú pé kò sí àníàní wí pé òun ní àwọn méjèèjì ń bú. Nítorí ìdí èyí, ó dámọràn wí pé kí bàbá òun ránńṣẹ́ pe ọkọ náà kí ó bà òun béèrè ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ, àti pẹ̀lú pé bí ọkùnrin náà kò bá lè sọ ohun tí ó ń pa á lẹ̀rìn-ín a jẹ́ wwí pé ó fi ojú di ọba. Nínú èyínìi pípa ni ọba nílátí pa á. Ẹyẹkòsọkà, ọba ti ránńṣẹ́ sí ọkùnrin yìí, nígbà tì ó dé tí ó sọ fún ọba pé òun kò lè sọ ohun ti ó ń pá òun lẹ́rìn-ín inú bí ọba ó sì wí fún un pé pípa ni òun ó pa á ọkùnrin náà sì gbà bẹ́ẹ̀ fún ọba. Wọ́n fún un láṣẹ kí ó lọ pa ilé rẹ̀ mọ́, wọ́n sí dá ọjọ́ pípa rẹ̀. Òun náà lọ sí ilé, ó kó gbogbo ìní rẹ̀ jọ, ó fi wọ́n fún ìyàwó tí ó kọ́ ní tí í ṣe ìyáálé fún oníkúpani obìnrin ọmọ-ọba nì, ó múra láti kú. Nígbà tí ó di ọjọ́ ikú rẹ̀, gbogbo ìlú pé láìku ẹnì kan ṣoṣo. Gẹ́gẹ́ bí àsà ìlù náà, wọ́n fún un ni àyè kí ó bá àwọn ará ìlú sọ̀rọ̀ kí ó tóo’kú. Nígbà tí ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ í sọ ẹ̀rú ba àwọn ará ìlú gidigidi. Ó sọ̀rọ̀ bí òun ti jẹ́ tálákà tẹ́lẹ̀ rí, tí tálákà òun pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò ní ju ìbàǹtẹ́ nínú ayé, tí ìyàwó òun kò ní ju yẹ̀rì lọ, tí owó ọwọ́ òun kò ju tọ́rọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣosọ, tí òun kì í sùn lóru nítorí ìrònú, tí ọkàn òun kì í balẹ̀, tí oúnjẹ òun kò níláári, tí ara òun gbẹ bíi igi. Àti bí ó jẹ́ pé alágùúgbò òun kan ló ṣàánú òun tí òun fi bẹ̀-rẹ̀ sí dá ẹmu, àti bí bí àgbọ̀nrín kan ti ń fọ òun ni akèǹgbè tí òun sì bẹ̀rẹ̀ sí lé e títí àwọn fi dé iwájú ogunlọ́gọ̀ àwọn ẹranko. Ó tún sọ bí òun tí ṣe ro ẹjọ́ òun níeájú àwọn ẹranko tí ó sì fi di pé wọ́n fún òun ní ẹ̀bún àti máa gbóhùn àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ, àti bí wọ́n sì ti kìlọ̀ fún pé ní ọjọ́ tí òun bá sọ àṣírí náà fún ẹlòmíràn ni òun yóò kú. Ó sì tún wáá sọ bí ó tí jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àwọn èkúté tí òun ń gbọ́ ni ó mú kí òun rẹ́rìn-ín tí ó sì di pé ìyàwó òun wí pé òun ń bú òun. Bí ọkùnrin yìí tí parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó ṣubú lulẹ̀ ó sì kú. Ìwọ ọ̀rẹ́ mi, nígbà tì ọkùnrin náà kú tán, wọ́n mú obìnrin nì, wọ́n sì so ó kọ́ sí orí igi. Bí ayé ti rí ni èyí, ìwọ ọ̀rẹ́ mi. Àwọn ẹlòmíràn á fi owó fẹ́ ikú wá ilé wọ́n á wí pé àwọn fẹ́ obìnrin, àwọn ẹlòmíràn a fi owó fẹ́ gbèsè wọ́n á wí pé àwọn fẹ́ ìyàwó, àwọn ẹlòmíràn á ti ìtirí wọ̀bìà wọn a sọ ìfẹ ìyàwó pàtàkì nù. Ọ̀rọ̀ ìyàwó kìí ṣe ọ̀rọ̀ ṣiréṣiré, ohun tí ó bá ilé ẹni lọ kúrò ní ọ̀rọ̀ yẹpẹrẹ. Bí ènìyàn bá ń fẹ́ẹ́ ní ìyàwó ó yẹ kí olúwaarẹ̀ ronú dáradára kí ó sì bẹ Olódùmarè kí Ó ṣe amọ̀nà òun, nítorí ìyá yátọ sí ìyàwó, bàbá yàtọ̀ sí obìnrin ẹni. Ìkarawun ni obìnrin, ìgbìn sì ni ọkùnrin, ibikíbi tí ìgbín bá ń lọ ti òun ti ìkarawun ní í lọ; ìyàwó bẹẹrẹ ìjàngbọ̀n bẹẹrẹ ni, bí ìyàwó bá ti ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ wọn ń dín sí i, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọkùnrin ni wọ́n sí ń bá ọ̀tá pàtàkì gbé tí wọn ń pè é ní obìnrin. ṣe bí o ti mọ, ìwọ ọ̀rẹ́ mi, rí i pé ìyàwó rẹ fẹ́ràn rẹ kí ó tóó wọ ilé rẹ. Lóòótọ́ ìwọ ni o níláti kọ wí pé kí ó fẹ́ ọ kí ó tóó fèsì fún ọ ṣùgbọ́n rí i pé òun pàápàá fẹ́ràn rẹ. Ìwọ náà kò sì gbọdọ̀ hùwà bí àwọn àgàbàgebè ọkùnrin tí àwọn obìnrin máa ń gbàdúrà rẹ̀ pé kí Ọlọ́run má ṣe jẹ́ kí ó dé sàkání àwọn. Bákàn náà ni, onílara pọ̀ púpọ̀ nínú ayé wa yìí kò sì sí ọ̀nà tí wọn kò lè gbè láti fi ìlara wọn hàn. Onílara ni ẹni tí inú rẹ̀ ń bàjẹ́ sí ìlọsíwájjú ẹlòmíràn, bí ènìyàn kan bá wà ní ipò olórí onílara a máa wá ọ̀nàkọ́nà láti fi hàn pé olúwaarẹ̀ kò tọ́ sí ipò náà òun a si gbàgbé pé ẹni tí Olódùmarè bá gbé ga kò sí ẹni tí ó lè rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ láéláé. Báyìí ni Baba-onírùngbọ̀n sọ̀rọ̀ tẹ̀, nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ wọn-ọnnì mo dáhùn, mo ní, Ọ̀rẹ́ ni ọ̀wọ́n, ọ̀rọ̀ rẹ ha parí ni èyíni bí? Máa bá a ǹṣó, ó ń dùn mọ́ mi, ọ̀rọ̀ rẹ ń wọ̀ mí létí, mo ń gbádùn ọ̀rọ̀ rẹ, ọ̀rẹ́ mi, Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ ọkùnrin. Lẹ́hìn eléyìí, Baba-onírùngbọ̀n dìde níbi tí ó jókòó sí ó sí tọ́ka sí igi kan tí ó ní òdòdó tí ó sì dára púpọ̀, ó wí pé: Wo igi tí ó wà lọ́hùn-ún nì; igi tí ewẹ rẹ̀ dúdú mirinmirin, lẹ́hùn-ún ni; tún wo òdòdó rẹ̀ bí o ti lẹ́wà tó pẹ́lú. Lẹ́hìn èyínì, wo apá ọ̀tún lẹ́bàá igi náà, ìwọ óò rí igi mìíràn tíó kéré díẹ̀, ìwọ yóó sì rí i pé àwọn méjèèjì jọ ara wọn. Kíyè sí àwọn méjèèjì dáradára, nítorí mo fẹ́ẹ́ sọ̀rọ̀ kan nípa won fún ọ. Nígbá tí ó wí báyìí tán èmi náà dáhùn, mo ní, Mo ti ri wọn, wọ́n jọ ara wọn, wọ́n dàbí ìbejì láàárin gogbo àwọn igi ti ń bẹ lágbègbè ibẹ̀. Nítorí náà, máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. Nígbà tí mo wí báyìí tán ọkùnrin náà tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní, Olówó-ayé, àwọn igi méjì tí iwọ rí wọn-ọnnì ènìyàn ni wọ́n jẹ́ rí. èyí tí ó dàgbà jù nínú àwọn méjèéjì ni ọmọkùnrin, èyí èkejì jẹ́ ọmọbìnrin. Àwọn méjì yìí fẹ́ràn ara wọn dé góńgó wọ́n sì ń fẹ́ láti fẹ́ ara wọn kí wọ́n di tọkọtaya. Ṣùgbọ́n òbí àwọn méjèèjì kò fẹ́ kí wọ́n fẹ́ ara wọn nítorí kò sí ìrẹ̀pọ̀ láàárin àwọn obì wọn-ọnnì. Síbẹ̀ àwọn ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin wọ̀nyí dàbí àhọ́n àti ẹnu sí ara wọn a sì máá bá ara wọn sọ̀rọ̀ ni ihò tí ń bẹ láti ògiri. Bí èyí ọmọbìnrin wọn bá gbé etí sí ẹnu ihò ní iyàrá tiẹ̀ ọmọkùnrin a máa sọ̀rọ̀ sí i lódì kejì, bí ọmọkùnrin bá gbé èti sí ẹnu ihò ni yàrá tirẹ̀ ọmọbìnrin a máa sọ̀rọ̀ sí i láti ọ̀hún wá. Ọ̀rẹ́ mi, èmi ni mo wí fún ọ, kò sí bí olùfẹ́ méjì ti lè wà kí wọ́n máà ní ìṣòro kan láàárin wọn. Ìfẹ́ kì í rìn láì ní ìkọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣùgbọ́n ìfẹ́ pípé a máa sọ òkè di pẹ̀tẹ́lẹ̀, a máa rìn láàrin ẹ̀gún láìbìkítà, a sì máa sáré tete láàárin kòtò àti gegele. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjì wọn-ọnnì pinnu àti sá kúrò ní ilé kí wọ́n lọ sí ìlú mìíràn ki wọ́n baà jọ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n rírò ni tti ènìyàn, ṣíṣe ni ti Ọlọ́run; ènìyàn mọ òní, Olódùmarè mọ ọ̀la, ó mọ ọ̀túnla, ó sì mọ ọ̀kẹ́ aàimọye ọdún tí ń bẹ níwájú wa. Àwọn ọmọdé méjì náà pinnu àti kúrò ní ilé ní alẹ̀, ní àkókò òṣìpá, wọ́n sì fi àdéhùn sí i pé kì àwọn pàdé ara àwọn léti odò kan, ẹni tí ó bá kọ́ dé ọ̀hún kí ó dúró de ẹni kejì, igbà tí àwọn méjèèjì bá pé sí etí odò náà kí àwọn máa sálọ, kí àwọn sì ti ipa bẹ́ẹ̀ bi ẹni tí ń gbé pọ̀ kí àwọn máa fi ìfẹ́ jẹ iyán, kí àwọn máa ffi ìfẹ́ jẹ ọkà, kí àwọn sì máa fi ìfẹ́ jẹ àkàṣù baba ẹ̀kọ. Nígbà tí ó di alẹ̀ ọjọ́ tí wọ́n dá, èyí obìnrin ló kọ́ dé etí odò yìí tíó ń dúró de olùfẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí ó dúró báyìí tí ó rí kìnnìún kan tí ó ń bọ̀, nígbà tí ó sì rí i ó sálọ fi ara pamọ́ sí inú ihò òkúta kan ṣùgbọ́n aṣọ rẹ̀ kan bọ́ sílẹ̀ nibi tí ó ti ń sálọ. Nígbà tí kìnnìún yìí dé ibi ti aṣọ yìí wà ó fi imú rùn ún, ó fi ẹnu rẹ̀ yí i, ẹ̀jẹ̀ sí bá aṣọ náà lára bálabála. Lẹ́hìn èyí, kìnnìún mu omi ó bá ihò rẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin yìí kò mọ ìgbà tí kìnnìún lọ, ó jókòó sí inú ihò lọ́hùn-ún. Láìpẹ́ lẹ́hìn èyí ọmọkùnrin dé, kò rí olùfẹ́ rẹ̀ obìnrin ṣùgbọ́n dípò èyìínì ó bá aṣọ olùfẹ́ rẹ̀ ní ilẹ̀ ó kún fún ẹ̀jẹ̀ bálabála. Nígbà tí ó rí eléyìí ó ṣe bí olúfẹ́ òun ti kú ni, ó bú sí ẹkùn kíkorò ó sì wí pé: Ó ṣe! Ó ṣe! Olúfẹ́ mi ti lọ! Kí ni ayé jẹ́ fún mi láìsí olùfẹ̀ mi! Olùfẹ́ mi ti bọ́ sí ọwọ́ ẹranko búburú, kìnnìún ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ta ni ó dà bí olùfẹ́ mi nínú ayé! Ta ni ó lẹ́wà bi ọmọ náà láàrin ọmọ ènìyàn! Ta ni ó lè ṣe bí òun ti í ṣe fún mi! Olúfẹ̀ mi, olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n jùlọ - lọ́jọ́ ìbànújẹ́ ìwọ fún mi láyọ̀; lọ́jọ́ ẹkùn ìwọ pa mí lẹ́rìn-ín; lọ́jọ́ ìbínú ìwọ lo tù mi nínú; lọ́jọ́ ìjà ìwọ lo fún mi ní sùúrù; lọ́jọ́ ìrẹ̀sílẹ̀ ìwọ lo gbé mi ga; nígbà tí àwọn ọmọ aráyé kọ̀ mí sílẹ̀ ìwọ kò kọ̀ mí; nígbà tí wọ́n ń bú mi ìwọ kò búu mi; nígbà tí wọ́n ń di r��kíṣí mọ́ mi ìwọ kò dì mọ́ mi – ìwọ ni mo fi ń ṣe iyì fún àwọn ọ̀rẹ́, ìwọ ni mo fi ṣe fọ́rífọ́rí fún àwọn ojúlùmọ̀, ìwọ ni mo fi ń ṣe ìlérí láàárin àwọn gbajúmọ̀ gbogbo. Bí ìwọ ti ń ṣe ojú mi ni ìwọ ń ṣe ẹ̀hìn mi pẹ̀lú. Ibikíbi tí ìwọ bá tí rí àwọn ènìyàn mi ni ìwọ ti ń yẹ́ wọn sí, nígbà tí àlejò mi bá dé ìwọ a máa ṣe é tayọ̀tayọ̀, ọjọ́ tí mo bá ríowó ni mo tó ń fi í fún ọ, ìgbà tí agbára mi bá ká ẹ̀bùn ni mo tó ń fún ọ ní ẹ̀bùn, ìwọ kò sì jẹ́ gbé ọ̀rọ̀ mi kalẹ̀ kí ó máa bú mi láàárin àwọn alábàáṣiré rẹ; ibi tí mo bá fi ọ́ sí ni mo máa ń bá ọ. O kò fẹ́ mi tán kí o tún máa bá ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ní kọ̀kọ̀, n kò sì bá ọ ní ìdí àgàgebè kan láti ọjọ tí a ti ń fẹ́ ara wa. O yẹ́ mi sí bí ó ti yẹ kí o yẹ́ mi sí, o bá mi siré nígbà tí iré tọ́, o bá mi kẹ́dùn ni àkókò ìbákẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ ni o kòo sì wí fún mi lọ́jọ́ kan wí pé kí ni mo máa ṣe. Kí ló ha tún kù fún mi lẹ́hìn irú èyí! Kí ló ha tún kù fún mi nígbà náà! Kí ìwọ lọ kí èmi jókòó sáyé àbí nla- Èmi kọ́. Ìjàpá kì í lọ kí igbá ẹ̀hìn rẹ̀ gbé ilẹ̀, ibi tí ìgbín bá ń lọ tòun tìkarawun ní ń lọ. Báyìí ni ọmọkùnrin yìí sọ, níbà tí ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, ó fa àdá yọ ó sì ṣá ara rẹ̀ lọ́gbẹ́ ni inú tó bẹ́ẹ̀ tí ìfun fi tú jáde: ikú dé. Bí ọkùnrin náà ti dákẹ́ gan-an ni olúfẹ́ rẹ̀ yìí jáde láti inú ihò ibi tí ó tí ó sá pa mọ́ sí. Ènìyàn kò lè fi ẹnu sọ ìbànújẹ́ náà tí tó nígbà tí ó rí òkú olúfẹ́ rẹ̀. Lójú kan náà ó ṣubú lulẹ̀ ọkàn rẹ̀ sì rẹ̀wẹ̀sì tó bẹ́ẹ̀ tí ó kú gbée. Ìtàn ikú wọn yìí gba ayé kan lákòókò náà Ọlọ́run Ọba sì yí àwọn méjèèjì padà sí igi méjì tí ìwọ ń wò ní, tí ewé wọn tutù bí ọ̀gẹ̀dẹ̀ etí odò tí òdòdó orí wọn sì ń mú òórùn d’;idùn jáde. Olódùmarè ti fi àwọn ẹ̀dá ọ̀run méjì sí ìdí igi wọn-ọnnì kí wọ́n máa ṣọ́ ibẹ̀ kí ohunkóhun máa baà pa wọ́n lára. Kíyèsí i, ọ̀rẹ́ mi, bí ìfẹ́ bá gbónà, ó dà bí omi òkun tí ń ru sókè tí ó sì ń bo yanrin mọ́lẹ̀, ìfẹ́ a máa bo ojú àwọn tí ń fẹ́ràn ara wọn. Ìfẹ́ dà bí ẹmu orí ọ̀pẹ ti ọkùnrin kan mu yó, tí ó bẹ̀rẹ̀ si pa á, tí ó sì sọ ọ́ di aṣiwèrè tí kò jẹ́ kí ó mọ èyí tí òun ṣe mọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin a máa kọ etí dídi sí àwọn ìbátan wọn ńigbà tí ìfẹ́ bá ru bò wọ́n lójú bí omi gbígbóná ti ń ru bo èlùbọ́. Ó yẹ kí ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin máa la ojú wọn sílẹ̀ dáradára kí wọ́n sì máa bẹ Ọlọ́run Ọba ki ó tọ́ wọn sí ọ̀nà kí ó tóó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ràn ẹnìkan. Ojú àti aṣọ ni púpọ̀ nínú àwọn ọmọdé ìwòyí ń wò tí wọ́n fi ń fẹ́ràn ènìyàn, ìwà òmùggọ̀ pátápátá gbáà ni. Ọmọ tí kò bá ronú jinlẹ̀ kí ó tóó jẹ́ kí ìfẹ́ gun òun bi ẹṣin, nígbà tí ìfẹ́ bá tì í sí kòtò tán, tapátẹsẹ̀ rẹ̀ ni yóò kún inú kòtò bámúbámú! Báyìí ni Baba-onírùngbọ̀n tún kọ́ mi ní ọgbọ́n pàtàkì lẹ́hìn tí ó ti pa’ri ìtàn rẹ̀ kejì yìí. Bí mo sì ti ń wò ó tí ó dákẹ́ mo ṣe ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀, mo ní, ‘Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ mi ọ̀wọ́n ò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ gidigidi – mo dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá. Bí ènìyàn bá ti ń ní ọjọ́ lórí tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ọgbọ́n orí rẹ̀ yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i. O kò béèrè ìdí rẹ̀ tí mo fi sọ bẹ́ẹ̀ ńdán? - Ẹnu ti ń yà mi láti ìgbà tí o ti ń sọ̀rọ̀ lónìi’tí mo ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ńlá tí ń bẹ lẹnu rẹ tí mo sì ń fiyè sí ọ̀rọ̀ pàtàkì tí ń bẹ ní ọ̀nà ọ̀fun rẹ. Nígbà tí mo sì ronú díẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí mo fẹ́rẹ́ lè sọkùn fún àwọn ọmọdé ìwòyí nítorí wọn kò bẹ̀rù àgbàlagbà mọ́, wọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n lójú ara wọn. Wọ́n ń kú bí iná, wọ́n sì ń ṣàìsàn láì-rò-tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ wọn kò jẹ́ ronú, ki wọ́n máa ṣe àkíyèsí ọ̀rọ̀ ẹ̀yin àgbàlagbà wọ̀nyí, kí wọ́n máa fi ọgbọ́n kún ọgbọ́n kí wọ́n máa ffi ìmọ̀ kún ìmọ̀, kí wọ́n mo ìtàkùn tí ó kọ́ àwọn ará ìṣáájú lẹ́sẹ̀ kí àwọn náà má baà ṣubú sínú ọ̀gbun. Bẹ́ẹ̀ ni irọ́ ni: àparò tí ó bá ń fi ara rẹ̀ wé àgbébọ̀ ń fi ikú ṣiré, ọmọdé tí ó bá ń fi ara rẹ̀ wé àwọn agbàlagbà ń fa ìjàngbọ̀n lẹ́sẹ̀ nítorí inú ọmọdé ń bẹ́ lóké bẹ́ẹ̀ ni inú àwọn àgbàlagbà jìn ó ju omi òkun lọ. Nítorí náà Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ mi ọ̀wọ̀n, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ gidigidi. Máa bá ọ̀rọ̀ rẹ ǹṣó, ó ń dùn mọ́ mi, kò sú mi. Nígbá tí mo wí b Ayìí tán ọkùnrin náà wò mí títí ó mi orí sókè-sódò, óo ní. Ìwọ ọmọdé yìí mà gbọ́n. Nígbà tí ó wí báyìí tán ó tún ń bá ìyókù ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, o ní, Olówó-ayé, nígbà tí mo bá ronú títí nígbà míràn, tí mo bbá ronú nípa aìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn àwọn ọmọ aráyé, a dà bí ẹni pé ẹni kan pàtàkì ti fi àwọn aráyé ṣẹ́ èpè ni. Àwọn ọmọ ènìyàn kò jẹ́ wí pé ibi tí àwọnn dé yìí tó, wọn a máa wí pé ó kù díẹ̀ títí ọjọ́ ikú wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá tún rò ó wò lọ́nà kejì mo tún rí i pé bí kò bá sí irú bẹ́ẹ̀ ayé pàápàá kì bá tí dùn tó bí ó ti dùn yìí. Síbẹ̀ náà ṣáá, ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ni ohun gbogbo. Jẹ́ kí á fi àwọn onígbàgbọ́ ṣe àpẹẹrẹ. Onígbàgbọ́ tí ó wà ní ipò akàwé nínú ìjọ, tí ó kúrò ní ipò èyìínì tí ó di àlùfáà tíi ó tún dé ipò bísọ́ọ̀bù tí kò ní ìẹ̀lọ́rùn, mo biọ́, eléyìínì ń fẹ́ẹ́ di Ọlọ́run ni? Tàbí onímàle di Àlàaájì, kí ó di Lèmọ́mù kékeré, kí ó tún kúrò nínú èyínìi kí ó di olórí fún àwọn Lémọ́mù, síbẹ̀síbẹ̀ kí ó tún máa nàgà, eléyìínì ń fẹ́ẹ́ di ànábì ni? – Àwọn ọmọ aráyè kì í ní ìtẹ́lọ́rùn rárá - ṣíọ́. Kíyè sí púpọ̀ nínú àwọn olówó, kìí ṣe gbogbo wọn, ṣùgbọ́n nígbà tí púpọ̀ nínú wọn bá ti di olówó tán àtijẹun sí ẹnu ara wọn a di nǹkan, wọn a bẹ̀rẹ̀ sí hùwà bí ẹni tí ènìyyàn ṣẹ́ èpè fún, wọn a máa wa gaàrí mu lọ́sàn-án, wọn a máa wa gaàrí mu lóru, títí ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn á fi di pẹlẹbẹ tí gbogbo ara wọn á sì gbẹ pátápátá bí ẹran tí ìyàwó mi sè ní ọbẹ̀ lálẹ̀ àná tí egungun rẹ̀ ń dún kérekéré lẹ́nu mi. Lóòótọ́ ó yẹ kí ènìyàn máa làkàkà láti ṣe nǹkan ńlá, kí olúwaarẹ̀ máa wá ìlọsíwájú fún ara rẹ̀, nítorí ẹni tí ó dúró sí ojú kan bí adágún omi kò sí láàárin àwọn alààyè, òkú ni eléyìínì láàárin wọn. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń na ọwọ́ rẹ̀ kò lè tó láéláé ìrù ló kù kí eléyìínì dì ọ̀bọ kí ó máa bẹ́ láti orí igi dé orí igi. Ọmọ Yorùbá tí kò bá ìdílé ọba tan, tí enì kan kò dé adé ní ìran rẹ̀ rí, tí ẹnikẹ́ni kò sì sọ ìtàn ìdílé rẹ̀ kan Ódùduà, tí ó tún fi ìlúrẹ̀ sílẹ̀ tí ó lọ sí ìlú òdì-kejì,tí ó dé ọ̀hún tán tí ó ńn ddu oyé wí pé òun fẹ́ẹ́ jẹ ọba, eléyìínì kò yàtọ́ sí ìnàkí àfi ti wí pé ara tirẹ̀ dán ju ti ìnàkí lọ. Ní ayé àtijọ́, nígbà tí ayé kò ì tí ì rí bàyìí, tí àwọn ọmọ ènìyàn mọ iyì Ọlọ́run ju ti ìwòyí lọ, Olódùmarè a máa ránńṣẹ́ láti ọ̀run wá láti wáá bẹ ará ayé wò, ìrańńṣẹ́ náà a sí máa wá lọ́dúun méje-méje. Ìrańńṣẹ́ náà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá ọ̀run, àwọn ará ayé a sì máa pè é ní Aṣojú-Olódùmarè. Àkókò tí ó bá wá, àkókò ńlá ni ó máa ń jẹ́ ní òde ayé, orin a máa kọlu orin, ìlù a máa kọlu ìlù, ijó a máa kọlu ijó, àwọn ènìyàn a sì máa ṣe àríyá pàtàkì gẹ́gẹ́ bí àmì ìyẹ́sí Ẹni tí ó dá wọn. Àkókò tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, Èṣù kò ì tí ì ní gbòǹgbò ní òde ayé, òun wà bí ẹ̀dá pàtàkì ní òde ọ̀ruin. Ṣùgbọ́n nígbà tí Èṣù gbé ẹebọ kọjá oríta, tí ó kọ etí dídi sí ọ̀rọ̀ Olódùmarè, àwọn ẹ̀dá òde ọ̀run lé jáde. Àkókò yìí ni Èṣù ri ọ̀nà láti ba ìgbésí-ayé ènìyàn jẹ́, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ ẹ́hìn wọn sí Ọlọ́run Ọba. Èṣù burú ju àwọn ẹ̀dá ìyókù lọ, nígbà tí òun sì ti gba ọkàn àwọn ènìyàn wọn-ọnnì, wọ́n ń wọ inú ẹ̀sẹ̀ bí ẹni ń wọ yàrá, wọ́n ń pòṣé sí Ọlọ́run wọn, wọ́n ń wí pé ipòo tí ó fi àwọn sí kò tó, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àìyẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá wọn. Nígbà tí ó tí aṣojú-Olódùmarè tún wáá bẹ̀ wọ́n wò, wọn kò yẹ́ ẹ sí bíi tí àtẹ̀yìnwá, nígbà tí òun sì bi wọ́n ìdí rẹ̀, wọ́n wí fún un pé ipò ti Ọlọ́run fí àwọn ssí kò tó, àwọn kò ní ìtẹ́lọ́rùn sí ipò àwọn. Ọlọ́run fẹ́ràn ènìyàn, A máá ṣe ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ. Ìgbà tí ẹ̀dá náà dé ọ̀run, tí ó jísẹ́ wí pé àwọn ọmọ aráyé kò ní ìtẹ́lọ́rùn, Ọlọ́run rán an padà kí ó lọ béèrè ohun tí olúkúlùkù wọn ń fẹ́,kí Òun baà lè ṣe é fún wọn. Nígbà tí Aṣojú-Olódùmarè padà dé òde ayé, ó lu agogo káàkiri òde, wwí pé kí olúkúlùkù wáá pàdé òun. Odidi ọdún mẹ́ta gbáko nni wọn ffi dá a dúró, tí wọ́n ń rán an níṣẹ́ sí òde ọ̀run. Onírúurú ni ìbéèrè wọn, ó sì pọ̀ ju ohun kíkà lọ. Síbẹ̀síbẹ̀ n ó sọ díẹ̀ nínú ìbéèrè wọn. Ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin tí ó wá sí iwájú Aṣojú-Olódùmarè ṣe ìbéèrè rẹ̀ báyìí, ó ní Ìwọ ìránńsẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé, ìwọ ìránńṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ọ̀run, ohun tí ó ṣe ẹ̀dùn ọkàn mi ni èyí, ipò tálákà tí mo wà yìí súu mi, kì í ṣe èmi nìkan ṣoṣo ní ń bẹ nínú ayé, tèmi ṣe kúkú le tó bẹ́ẹ̀? Lọ́jọ́ àìríjẹ, lọ́jọ́ àìrímu, lọ́jọ́ àìrí-nǹkan-bora, tèmi yìí pọ̀ jù, jọ̀wọ́ bá mi wí fún Ọlọ́run Ọba kí ó ṣàánú kí ó fi mí sí ipò tí ó sàn ju eléyìí lọ. Ẹni kejì tí ó tún wá sí ọ̀dọ̀ Aṣojú-Olódùmarè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tirẹ̀ báyìí, ó ní ‘Ìwọ ìranńṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé, ìwọ ìranńṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ọ̀run, bá mi wí fún Ọlọ́run Ọba kó Ó gba ọ̀rọ̀ mi yìí yẹ̀wọ̀, ẹni tí ó jẹ́ ọ̀gá fún mí ní ibi iṣẹ́ burú bí ejò olóró, ó ní ìkà bí ẹni pé òun pàápàá kì í ṣe ènìyàn, ó le bí òkúta. A máa rán mi ni iṣẹ́ lọ́sàn-án a máa rán mi ni iṣẹ́ lóru, a máa rán mi ní ìṣẹ́ ní ìkọ̀kọ̀, amáa rán mi ní iṣẹ́ ní gbangba, kò kí mi ‘kú iṣẹ́’ lọ́jọ́ kan rí a sì máa fa ojú ro láti òwúrọ̀ di ojú alẹ̀ koko, nítorí èmi bẹ̀ ọ́, bá mi wí fún Ọlọ́run Ọba wí pé kí Ó fi mí sí abẹ́ ẹlòmíràn tí yóó maa ṣe ìtọ́jù mi. Ẹni kan wá sí ọ̀dọ̀ Aṣojú-Olódùmarè, nígbà tí ó sí bẹ̀rẹ̀ si ọ̀rọ̀ í sọ, ó ni, ìwọ ìránṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé, ìwọ iranṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ọ̀run, bá mi wí fún Ọlọ́run Ọba pé, ìyàwó tí mo ní kò fún mi ní ìtẹ́lọ́rùn kan ṣoṣo, ìyàwó náà ló tilẹ̀ kọ́ ń wá ojú mi mọ́ra, n kò kọ́ ní èrò àti fẹ́ ẹ. Nígbà tí alákọri sì dé ilé tán ńkọ́, kò tilẹ̀ mọ fáàrí kan ṣoṣo í ṣe, kò bá ayé ìwóyí mu, aṣọ rẹ̀ kò dára tó, ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ kò gbádùn, oúnjẹ rẹ̀ kò sì lọ dáádáá ni ọ̀nà ọ̀fun. Kò lè sọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu ju bẹ́ẹ̀ lọ, gbogbo ilé a máa dákẹ́ minimini. Aláìsàn ènìyàn ni obìnrin náà,ojoojúmọ́ ni mo ń ti ilé babaláwo dé ilé babaláwo. Lórí gbogbo rẹ̀ tálákà ni ìrandiran rẹ̀, wọn kò ní nǹkan kan. Ọ̀rẹ́ mi tíó ń gbé etí ilé mi kò ní eépìnní rí, baba ìyàwó rẹ̀ ní ó sọ ọ́ di ènìyàn, tí ó fi owó ńlá dúró fún un lọ́dọ̀ Òyìnbó,ìgbà tí mo sì rí tọkọ-taya náà láì pẹ́ yìí, ṣe ni àwọn mejèèjì fẹ̀hìntì sí inú mọ́tò ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n ń lọ gẹ́gẹ́ bí ọba. Nítorí náà èmi bẹ̀ ọ́, ìwọ ẹ̀dá pàtàkì tí í ṣe Aṣojú-Olódùmarè, bá mi wí fún Ọlọ́run Ọba wí pé kí Ó gba ìyàwó éléyìí kí ó fi fún ẹlòmíràn kí ó bá mi wá ìyàwó tí yóò mọ́ mi lára. Alákọ̀wé kan tọ aṣojú-Olódùmarè wá, ọkùnrin tí a ń wí yìí jẹ́ olùkọ́ ilé-ìwé, nígbà tí ó dá ọ̀dọ̀ Aṣojú-Olódùmarè tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ í sọ, ó ní, ìwọ ìránṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé, ìwọ iranṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ọ̀run, bá mi wí fún Ọlọ́run Ọba wí pé iṣẹ́ tí mo ń ṣe yìí kò tẹ́ mi lọ́rùn rárá. Nítorí wí pé owó mi kò tó, àwọn ọmọdé kò fi mi lọ́kàn balẹ̀, ojoojúmọ́ ni mo si tún níláti máa kọ̀wèé, tí orí mi ń gbóná janjan. Àwọn ẹni tí a jọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nígbà kan náà ti sanra nísisìyí, ẹ̀hìn ọrùn wọn ti tóbi, orúnkún wọn lásán sì ti tóbi ju ibàdí mi lọ. Bẹ́ẹ̀ ni èmi nìyí, tí mo rí tẹ́ẹ́rẹ́ bí ejòi, tí n kò sanra bí ekòló, tí mo ń rìn táńpẹ́-táńpẹ́ kiri. Nítorí náà èmi bẹ̀ ọ́, bá mi wí fún Ọlọ́run Ọba pé, kí ó wá iṣẹ́ mìíràn fún mi. Bí ọkùnrin yìí ti sọ ti ẹnu rẹ̀ tán ni ọkùnrin mìíràn tún ti bọ́ síwájú tí ó wólẹ̀ níwájú Aṣojú-Olódùmarè, ó wí pé ìwọ ìránṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé, ìwọ iranṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ọ̀run, bá mi wí fún Ọlọ́run Ọba pé ọmọ tí ó fún mi yìí kò tẹ́ mi lọ́rùn rárá, ki ó ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ̀ fún mi, ọmọ tí óo le koko bí òkúta amáa gun igi dé ṣóńṣó orí, a máa ti ibi gegele bẹ́ lé ibi gegele, a máa wẹ̀ nínú odò jíjìn a máa lé ewúrẹ́ káà kiri ilé, a máa sọ òkò lu àgùntàn káà kiri ojú ọ̀nà, a máa lé ọmọ ọlọ́mọ káà kiri òde. Orí rẹ̀ bí òkúta, kò mọ ìwé olóókan, àfi bí ó ń ya àwòrán kiri. Ìwé tí mo rà fún un ní àìpẹ́ yìí ó ti sọ ọ́ nù, ẹ̀wù tí mo rà fún ùn ní ijọ́sí ó ti fà á ya, ẹni tí ó jẹ́ alága ní ìdí ìrẹ̀sì, baálẹ̀ gaàrí, ọba nínú iyán, ènìyan pàtàkì ní ìdí ọbẹ̀, ẹni tí ì ṣe ọ̀rẹ́ oóúnjẹ, ọ̀tá ẹni tí ń ṣiṣẹ́, ọ̀rọ̀ ọmọ náà pọ̀ ju ohun kíkà lọ, nítorí náà, ìwọ ẹbọra òde ọ̀run, má ṣáí bá mi wá ibi tí n óò gbé ọ̀ràn yìí kà, ènìyàn rírọ̀ ló wù mi, n kò fẹ́ aláìgbọ́ràn ọmọ. Lẹ́hìn eléyìí ọkùnrin kan tún wá síwájú Aṣojú-Olódùmarè, akọ̀wé kan báyìí ni, nígbà tí ó dé pẹ̀lú ìtara ni ó fi ń sọ̀rọ̀, tí ó ń fi orí sọ tí óo ń fi ọrùn sọ, ó ní, ìwọ ìránṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé, ìwọ iranṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ọ̀run, bá mi wí fún Ọlọ́run Ọba pé, kí Ó ba mi yí àwọn aláṣẹ ní ibi iṣẹ́ mi lọ́kàn padà, kí wọ́n yéé ṣí mi ní ipò padà lọ́dọọdún: kí n máa ti ìlú dé ìlú, kí n máa tí ìletò dé ìletò, kí n máa bá hílàhílo kiri; bí wọ́n tí ń ṣe mi yìí kò dára. Àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí mo ní nígbà tíi mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ti bàjẹ́ tán, wọ́n ń bàjẹ́ ní ojú ọ̀nà nibi tí mo gbé ń di ẹrù kiri; ìkòkò ìyàwó mi méjìlá ti fọ́, àádọ́jọ ṣíbí ti sọnù, àwọn ọmọdé kò rí ẹni sùn mọ́, ohun ọ̀ṣọ̀ ilé ń din lójoojúmọ́, a kò lè ka àwọn nǹkan kéékèèkéé tí a kò mọ ọ̀nà tí wọ́n gbà lọ, nígbà tí a bá sì ń fẹ́ẹ́ gbádùn àwọn ọ̀rẹ́ wa ní ibi kan ni wọ́n máa ń yà wá ni ipa kúrò lọ́dọ̀ wọn. Nítorí náà èmi bẹ̀ ọ́, bá mi wí fún Ọlọ́run Ọba wí pé kí Ó wá ọ̀gá mìíràn fùn mi, bí bẹ́ẹ̀ bá sì kọ́, kí Ó yí àwọn ọ̀gá mi wọ̀nyí lọ́kàn padà, kí wọn máa wo ti ìyàwó mi, kí wọ́n ṣàánú àwọn ọmọdé, kí wọ́n sì ronú nípa àwọn ojúlùmọ̀, kí wọ́n yéé gbé mi kiri. Ẹnìkan báyìí tí n óò tún sọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ọkùnrin kan tí ó ṣe ìbéèrè tí ó jọ gbogbo ènìyàn lójú gidigidi. Nígbà tí ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ í sọ o dáhùn, ó ní, ìwọ ìránṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé, ìwọ iranṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ọ̀run, ohun tí mo fẹ́ẹ́ béèrè jẹ́ ìṣoòro, ṣùgbọ́n mo bẹ̀ ọ́, má ṣàì ṣe ó fún mi. Bá mi wí fún Ọlọ́run Ọba pé ìlú tí Ó jẹ́ kí wọ́n ti bí mi kò tẹ́ mi lọ́rùn, mo ń fẹ́ kí ọmọ aráyé máa pè mí ní ọmọ ìlú mìíràn, n kò fẹ́ kí ẹikẹ́ni mọ ìlú náà pẹ̀lú mi. Láti ọjọ́ tí wọ́n ti bí mi níbẹ̀ n kkò gbádùn rárá: ọmọ méje ni mo bí, méjì ti kú nínú wọn, ó dá mi lójú pé àwọn èjẹ́ ló pa méjì náà jẹ́. Iṣẹ́ àgbẹ̀ tí mo ń ṣe kò ṣe mí ní àǹfààní nítorí ilẹ̀ náà kò dárá – iṣu kò ta, ọ̀gẹ̀dẹ̀ kò yọ ọmọ, ẹ̀gúsí kòo so, n kò sì ń rí ju àgbọ̀n erèé méjì lọ̀dún kan. Lẹ́hìn èyí mo rí pọ́nùn mẹ́wàá kan yá lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ mi mo si bẹ̀rẹ̀ sí fi i ṣòwò, mo jèrè títí mo fi san owó náà tán mo sì ṣe bẹ́ẹ̀ mo kọ́ ilé, lẹ́hìn èyí mo ra mọ́tò mo sì ń di ẹni tí ń gbádùn ayé mi díẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ará ìlú náà kò dára, wọ́n ki ojú bọ̀ mí lára; nígbà tí ó ṣe mọ́tò mikan bàjẹ́, kò sí pẹ́ lẹ́hìn náà èkejì kọlu igi kan ó sì rún wómúwómú, Ọlọ́run ló tilẹ̀ yọ mí tí ẹnikẹ́ni kò kú sí i. Síbẹ̀ mo náwó lórí ọ̀rọ̀ náà kí n tóó lè yọ. N kò lè sọ iye àwọn ẹ̀gbọ́n, àbúrò, ìbátan, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ mi tí ń kú lọ́dọọdún. Họ́wù o, èmi nìkan ló wà láyé ni? Èyí tí ó tilẹ̀ tún burú jù ni pé ìlú náà pàápàá ti kéré jù wọn kò sì tilẹ̀ mọ́ ọn níbòmíràn jù bẹ́ẹ̀ lọ, ojú a sì máa tí mí ní ìdálẹ̀ nígbà tí wọ́n bá béèrè ìlú mi. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́ tọ́kàntọ́kàn, bá mi wí fún Ọlọ́run Ọba pé kí ó fi ìlú mìíràn fún mi kí wọ́n sì kéde fún àwọn ọmọ ènìyàn pé ìlú burúkú yìí kì í ṣe tèmi mọ́, àti pé ìbòmíràn ní a gbé bí mi. Báyìí ni gbogbo àwọn ènìyàn wọnn-ọnnì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ohun tí wọ́n ffẹ́, nígbà tí ó ṣe, Aṣojú-Olódùmarè wí fún wọn pé kí olúkúlùkù máa ṣe ìbéèrè nípa àìsàn rẹ̀ ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé ẹni tí ó ba fẹ́ láti fi àìsan kan silẹ̀ níláti béèrè òmíràn dípò rẹ̀ tí wọ́n fi ara wé ara wọn nípa ibi tí wọ́n ń ṣe. Nígbà tí àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìbéèrè nípa àìsàn, wọ́n yí aṣojú-Olódùmarè ká, wọ́n bò ó bi ìgbà tí ogunlọ́gọ̀ àwọn èèrà bá bo ẹ̀rún oúnjẹe, wọ́n ń sọ̀rọ̀ bí ìgbà tí àwọn ẹyẹ ẹ̀gà bá ń ké lórí ọ̀pẹe, wọ́n ń rín síhìn-ín rìn sọ́hùn-ún bí ìgbà tí alápàádẹ̀dẹ̀ bá ń fò káà kiri ẹ̀hìnkùnlé, wọ́n ń ro ẹjọ́ bí ẹni pé Ẹni tí Ó dá wọn kò gbọ́n tó wọn. Ẹlòmíràn fi orí-fífọ́ sílẹ̀ ó béèrè inú-rírún, òmíràn fi ẹ̀hìn-dídùn sílẹ̀ ó béèrè ẹsẹ̀-dídùn, afọ́jú mìíràn ń béèrè etí-dídi, onísòbìyà míràn ń béèrè làkáràgbé, adẹ́tẹ̀ míràn ń béèrè wárápá - ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ náà fún àwọn aráyé, wọ́n tú àṣírí tí Olódùmarè fi sí ìpamọ́ fún wọn. Lẹ́hìn èyí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àròyé fún aṣojú-Olódùmarè nípa ẹwà ara wọn. Àwọn obìnrin ló pọ̀ níbẹ̀ jù lákòókò yìí, etí ènìyàn gbọ́ nǹkan. Ẹlòmíràn a wí pé orí òun tóbi jù òun ń fẹ́ kí ó túbọ̀ kéré sí i, òmíràn a wí pé etí òun tóbi ju bí òun ti fẹ́ òun kò fẹ́ irú etí bẹ́ẹ̀ mọ́, ẹlòmíràn a wí pé ẹsẹ̀ òun tẹ́ẹ̀rẹ́ ju bí ó ti yẹ òun ń fẹ́ kí ó tóbi díẹ̀ sí i. Ẹlòmíràn ń ṣe àròyé nípa irun orí òun wí pé kò pọ̀ tó òmíràn a wí pé irun orí kò dúdú tó bí ó ti yẹ bẹ́ẹ̀ ni òmíràn ń ṣe àròyé wí pé irun tí ó ti pọ̀ ri bẹ̀rẹ̀ sí dínkù. Ẹlòmíràn ń tọrọ ojú mìíràn nítorí ojú tí ó ńi kò tẹ́ ọ lọ́rùn, òmíràn ní ojú òun dàbí ojú ajá, òmíràn fi ojú ara rẹ̀ wé ojú mààlúù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe àròyé nípa ojú ara wọn. Àwọn ẹlòmíràn kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ojú rárá ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnu, wọ́n ń wí pé ẹnu àwọn rí pẹlẹbẹ, ẹnu àwọn rí gbẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀, ẹnu àwọn rí róbótó àti wí pé eyín ẹnu àwọn ń pupa. Báyìí ni àwọn ọmọ aráyé bẹ̀rẹ̀ sí ṣe tí wọn ń sọ̀rọ̀ tí wọn ń dárúkọ orí kékeré àti ọwọ́ títóbi, bẹ́ẹ̀ náà ssì ni aṣojú-Olódùmarè fi etí sílẹ̀ tí ó ń gbọ́ àròyé wọn. Nígbà tí àwọn ọmọ aráyé sọ̀rọ̀ ẹnu wọn tán ẹ̀dá náà dìde ó wí fún wọn kí wọn máa lọ si ilé àti wí pé nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì olúkúlùkù yóó rí i pé ohun gbogbo tí òun béèrè ni òun ti rí gbà. Kí gbogbo wọn tóó túká ó wí fún wọn pẹ̀lú pé ìgbà tí ó bá di ọdún kẹrìnlá lẹ́hìn náà ni òun óò tún padà wáá bẹ́ wọ́n wò ní òde ayé kí òun wáá gbọ́ bí wọ́n tí ń gbádùn nǹkan tuntun gbogbo tí wọ́n béèrè sí. Nígbà tí ó wí báyìí tán àwọn \moọ aráyé bá inú ayé lọ òun náà sì bá òde ọ̀run lọ. Lóòótọ́ ọ̀rọ̀ tí ẹ̀dá yìí wí ṣẹ: ní ọjọ́ kejì ni nǹkan gbogbo ti rí bí ó tí wí tí olúkúlùkù bá ara rẹ̀ ní ipò tí ó béèrè. Ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu jùlọ pátápátá ní èyí pé ọ̀sẹ̀ náà kò ì tí ì parí nígbà tí àwọn ọmọ aráyé tún ti bẹ̀rẹ̀ sí àròyé wọn. Wọ́n ń tún fẹ́ẹ́ padà sí ipò wọn ìṣáájú, nígbà tí ó sì fi máa tó ọdúun mẹ́ta lẹ́hìn èyí igbe ti gba gbogbo inu ayé kankan. Nígbà tí ó máa fi tó ọdún mẹ́fà wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ètùtù, wọ́n ń rúbọ sí Ọlọ́run Ọba wí pé kí Ó jẹ́ kí aṣojú-Olódùmarè tètè padà kí ó wáá fi àwọn sí ipò tí àwọn ti wà ri. Wọ́n gbìyànjú àti yí Olódùmarè padà kúrò nínú ìpinnu tẹ̀ ṣùgbọ́n kò ṣe é ṣe. Wọ́n fi ewúrẹ́ rúbọ, wọ́n fi àgùntàn rúbọ, wọ́n pa mààlúù sí oríta, wọ́n pa àkùkọ, wọ́n pa àgbébọ̀, wọ́n sì fi odidi ènìyàn ṣeẹbọ, ṣùgbọ́n síbẹ̀ Olódùmarè kò rán ẹ̀dá náà wá àfi ìgbà tí ọdún mẹ́rìnlá tóó pé. Nígbà tí Aṣojú-Olódùmarè dé gbogbo àwọn ọmmọ aráyé tún péjọ, ipò wọn tí wọ́n tí wà kò tún tẹ́ wọn lọ́rùn mọ́, ogunlọ́gọ̀ tún ń fẹ́ẹ́ padà sí ipò rẹ̀ àtẹ̀hìnwá. Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ba ni lẹ́rù gidigidi; mo sì fẹ́ẹ́ sọ díẹ̀ nínú àyípadà tí ó dé bá wọn. Ẹni tíó béèrè ọmọ mìíràn tí ó wí pé ọmọ òun kò mọ ìwé ti ní ọmọ mìíràn tí ó mọ ìwé ṣùgbọ́n ọmọ tuntun yìí ti wọ inú ��̀wọ̀n kí Aṣojú-Olódùmarè tóó dé nítorí ẹni tí ó mọ ìwé tí kò ní ìwà burú ju ẹni tí ó ní ìwà tí kò mọ ìwé lọ. Àwọn ọmọ̀wé tí wọ́n ti ṣo ìwà wọn nù ni àwọn ejò olóró ní inú ayé tí wọ́n ń bu aláìṣẹ̀ jẹ káàkiri òde, bẹ́ẹ̀ ni ojú wọn ti fọ́ wọn kò sì mọ̀, wọ́n wà ní ipò afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han ẹni tí ó ríran. Ọkùnrin tí ó wí pé ọmọ òun kò mọ ìwé nígbà tí aṣojú-Olódùmarè kọ́ wá rí i pé ọmọ tí òun kọ̀ sílẹ̀ ní ìjọ́ sí ti di ènìyàn pàtàkì. Irun orí lásán ni ó ń gé fún àwọn ẹlòmíràn ní ìṣáájú, ṣùgbọ́n ó tọ́jú iṣẹ́ ó sì tọ́jú òwò rẹ̀. Nígbà tí ó ṣe ó bẹ̀rẹ̀ sí fi owó náà ṣòwò, òwò náà sì lọ síwáju dáradára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ní àkókò tí Aṣojú-Olódùmarè fi máa padà de irin wó ọ̀mọ̀wé ni ó jẹ́ akọ̀wé ní abẹ́ ọmọ yìí bẹ́ẹ̀ ni òun ni ó ni owó tí ó san fún wọn. Ó ti di ọ̀gá àwọn ọ̀mọ̀wé wọn-ọnnì ṣe ni wọ́n ń ká ọwọ́ sí ẹ̀hìn bí wọ́n bá ń bá a sọ̀rọ̀, wọn a máa sáré nígbà tí ó bá pè wọ́n, wọn a sì máa yẹ́ ẹ sí nígbà tí ó bá dé ọ̀dọ̀ wọn. Ọkùnrin kan tí ó wí pé òun ń fẹ́ẹ́ di olówó ti di olówó kí Aṣojú-Olódùmarè tóó dé ṣùgbọ́n inú àìsàn ní ẹ̀dá ọ̀run náà bá a nítorí nígbà tí ó di olówó tán kò mọ àwọn àgblagbà mọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí yáájú sí gbogbo àwọn ènìyàn kiri, àṣẹ̀hhìnwá-àsẹ̀hìnbọ̀ àìsàn kan kọlù ú bẹ́ẹ̀ ni dókítà kò sí ní ìtòòsì, àwọn àgbàlagbà tí wọ́n sì mọ oògùn àti ràn án lọ́wọ́ nítorí ó ti yáájú si gbogbo wọn. Lọ́nà kejì, kí àìsàn yìí tóó ṣẹlẹ̀ ẹ̀ẹ̀mẹta ni àwọn olè ń fẹ́ẹ́ pa á tí ọwọ́ kò bà á, ní ẹ̀ẹ̀kẹta wọn ṣá a lọ́gbẹ́ ṣùgbọ́n ọwọ́ kò rí àyè bà á dáadáa ṣùgbọ́n síbẹ̀ náà wọ́n gé àtàǹpàkò ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún sọnù, ibi tí ó sì ti ń sá lọ ó jìn sí kòtò eguneegun ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún sì rún wómúwómú. Lórí gbogbo rẹ̀ ìdánwò ni owó-níní jẹ́ fún un bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí kò ṣe dáadáa nínú ìdánwò náà, nígbà tí ó di olówó tán ó fẹ́ ogunlọ́gọ̀ obìnrin. Kò wo ìwà wọn tí ó fi ń fẹ́ wọn, ẹwà ara àti títóbi ìdílé ni ó ń wò tí ó fi ń fẹ́ wọn, ṣùgbọ́n ní àkókò tí Aṣojú-Olódùmarè fi máa padà dé, ọkàn ọkùnrin náà kò balẹ̀ nínú ilé, ilé rẹ̀ kún fún ariwo, ìjà, ìbànújẹ́ àwọn ará ilé náà kò fi ara wọn ṣe ọ̀rẹ́, wọ́n jẹ́ ọ̀tá pàtàkì fún ara wọn. Ọ̀kan nínú àwọn tí ó tún ṣe àròyé fún Aṣojú-Olódùmarè lẹ́ẹ̀kejì yìí ni ọkùnrin kan tí ó kọ́ wí pé ìwà ọ̀gá òun le púpọ̀, ó tí bọ́ sí ọ̀dọ̀ọ̀gá mìíràn tí ó tuutù ju omi àmù lọ, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn bẹ̀rẹ̀ sí rẹ́ ọkùnrin yìí jjẹ, ìwọ̀sí tí wọn kò sì fi lọ̀ ọ́ nígbà tí ó wà lábẹ̀ ọ̀gá líle ni wọ́n fi ń lọ̀ ọ́ nígbà tí ó bọ́ sí abẹ́ ọ̀gá rírọ̀ yìí, kò sì ní ìlọsíwájú kan ṣoṣo. Èyí tí ó wí pé ìyàwó òun jẹ́ ọmọ tálákà ti lọ fẹ́ ọmọ olówó kan ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà fi máa yọ sí Aṣojú-Olódùmarè, kò ju pàṣán lọ nítorí ọkàn rẹ̀ kò bálẹ̀. Ìyàwó náà fi ojú rẹ̀ rí nǹkan: kò gbọ́ràn kò bìkítà, a máa ro ẹjọ́ lójoojúmọ́, ìgbà tí ó bá wù ú ní ó ń jáde nínú ilé ìgbà tí ó bà sì wù ú ni ó ń padà bọ̀ bẹ́ẹ̀ ni òun ni ẹni tí ń pa àṣẹ fún ọkọ. Ẹni tí ó wí pé iṣẹ́ olùkọ́ kò wu òun mọ́ wí pé òun ń fẹ́ẹ́ ṣe akọ̀wé bá ara rẹ̀ ní ibi iṣẹ́ akọ̀wé nítòótọ́ ṣùgbọ́n nígbà tí ó kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ilé tí ó ti ń ṣiṣẹ́ kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àwọn akọ̀wé jẹ́ ẹgbẹ̀rún bẹ́ẹ̀ ni òun sì ni ìkẹhìn gbogbo wọn; iṣẹ́ rẹ̀ kò lọ déédéé nítorí kò ní ẹ̀bùn iṣẹ́ tí ó wọ̀ ọ́ lójú yìí bẹ́ẹ̀ ni kò bá àwọn ọlọgbọ́n ibi iṣẹ́ yìí rìn ó ń ṣe bí àwọn ọmọ olówó láìní owó lọ́wọ́, àwọn tí kò gbẹ́kẹ̀lé owó oṣú nìkan tí wọ́n tún ń gba owó mìíràn lọ́wọ́ bàbá wọn bẹ́ẹ̀ ni onírúurú ènìyàn tí ó wà ní ibi iṣẹ́ yìí jẹ́ ìdánwò fún ọkùnrin náà, nígbà tí Aṣojú-Olódùmarè sì fi máa padà dé, inú gbèsè ni ó bá a. Ọkùnrin tí ó béèrè ní ìṣáájú pée kí ọ̀gá òun yéé máa gbé òun láti ìlú kan dé ìlú kan wéréwéré kò í tí ì fi ìlú tí ó ti wà kí Aṣojú-Olódùmarè tóó wá ní ìṣáájjú sílẹ̀. Fún odidi ọdún mẹ́rìnlá tí ẹ̀dá náà ffi wà ní òde ọ̀run wọn kò yí ọkùnrin náà ní ipò padà. Ìlú náà kò sí ní gbańgba, ibi ìkọkọ̀ kan báyìí ni ó wà, ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ gbúròó ọkùnrin náà mọ́. Ọ jókòó sí ọ̀hún ó ddà bí ọba láàárin àwọn ènìyàn, ìgbéraga wọ̀ ọ nínú ọkàn lọ òun sì bẹ̀rẹ̀ sí rò nínú ara rẹ̀ pé kò sí ẹni tí ó dàbí òun. Iṣẹ́ ọkùnrin náà kò hàn sí òde jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbà tí wọ́n bá sì ń gbé àwọn ẹlẹgbọ́ rẹ̀ sí ìwájú wọn kò ní í gbé òun nítorí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí àwọn olórí bá lọ bẹ ọkùnrin náà wò a máa gbéraga sí wọn nítorí tí kò mọ̀ pé iṣẹ́ òun kò dára tó ti àwọn ará ibòmíràn, ó jókòó sí ìlú kan, kò jẹ́ jáde sí gbángba, òun kò mọ̀ wí pé ẹni tí ó fi inú iyàrá ṣe ibùgbé ọgbọ́n iyàrá nìkan ni yóò ní mọo. Ibi tí ọkùnrin yìí rò pé ayé ti ti ibẹ̀ sílẹ̀, nígbà tí Aṣojú-Olódùamrè dé tí ọkùnrin náà jáde wá sí ààrin àwọn ènìyàn, ó ti re ẹ̀hin pàtàpàtà, ojú bẹ̀rẹ̀ sí tì í ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ kò dà bí ìrìn ẹsẹ̀ ọmọ ènìyàn, ó dàbí ẹranko tí ó gbé àwọ̀ ènìyàn bora. Bákan náà ni ẹni tí ó wí pé ìlú òun kò dára àti pé òun ń fẹ́ẹ́ dì ọmọ ìlú mìírà. Lóòótọ́ ó di ọmọ ìlú mìíràn ṣùgbọ́n láàárin ọdún mẹ́ta ni gbogbo ọmọ rẹ̀ kú tán, atẹ́gùn ìlú náà kò bá a lára mu. Ìyàwó rẹ̀ pàápàá kú bẹ́ẹ̀ ni àwọn ara ìlkú náà kò fẹ́ràn rẹ̀, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń di rìkíṣí mọ́ ọn. Oúnjẹ wọ́n bí ojú iṣu kan jẹ́ pọ́nùn kan, garawa epo jẹ́ pọ́nùn mẹ́fà, páànù èlùbọ́ jẹ pọ́nùn méjì, àkùkọ adíẹ̀ si jẹ́ pọ́nùn méje. Bẹ́ẹ̀ ni ìgbásí-ayé ọkùnrin yìí burúu tó bẹ́ẹ̀ tí ayé sú u pátápátá, ọ̀run sì bẹ̀rẹ̀ sí wù ú lọ. Nígbà tí Aṣojú-Olódùmarè fi máa dé púpọ̀ nínú àwọn aláìsàn ti kú, ara wọn kò lágbára láti gbé àìsàn tí wọ́n béèrè nígbà tí òun kọ́ wá. Àwọn tí ó béèrè ẹwà ara kábàámọ́ gidigidi, ẹlòmíràn tí ó wí pé orí òun tóbi jù ti rí orí mìíràn tí kò ju èèso òroǹbó lọ, èyí tí ó wí pé ẹsẹ̀ òun tẹ́ẹ́rẹ́ ti rí ẹsẹ̀ míràn tí ó dà bí ẹsẹ̀ erin, olójú kékeré ní ojú tì ó dà bí ojú agogo, olójú títóbi sì rí ojú tí ó dà bí ti adìẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni nǹkan náà rí jágbajàgba réderède, nítorí Ọlọ́run Ọba kò dá nǹkan tí àwọn ọmọ ènìyàn ń béèrè wọn-ọnnì mọ́ wọn. Ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ọmọ aráyé ṣe ìbéèrè rẹ̀ tán tí wọ́n wí fún Aṣojú-Olódùmarè pé àwọn kò fẹ́ nǹkan tí àwọn kọ́ béèrè mọ́, ara ọ̀run yìí bú sí ẹ̀rín, ó dáhùn ó sì wí pé: Ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ẹni tí Ó jẹ́ alákòóso ẹ̀dá gbọ́n ju àwọn ẹ̀dá ìyókù lọ! - Ẹ lọ ṣe àkíyèsí àwọn ewé orí igi, kí ẹ wo ìlà kéékèèkéé tí Ọlọ́run Ọba fi sí ara wọn, ẹ lọ wo àwọn ẹranko inú igbó, bí wọ́n ti pọ̀ tí wọ́n lágbára tí wọ́n ń bá ọ̀nà tí Ẹlẹ́dàá wọn fi ẹsẹ̀ wọn lé lọ, ẹ kíyè sí ogunlọ́gọ̀ ejò tí ń bẹ ní inú ayé, ẹ wo àwọn kòkòrò bí wọ́n ti pọ̀ tó, ẹ wo onírúurú ẹja, ẹ wo ọ̀pọ̀lọ́ tí ń gbé orí ilẹ̀ tí ó tún ń gbé inú omi. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé Ẹni tí Ó ṣe àwọn nǹkan wọnn-ọnnì ta àwọn ẹ̀dá ìyókù yọ! - Ẹ̀yin ọmọ ẹnìyàn, bí ẹ bá ń múra àti lọ síwájú nǹkan rere ni; ṣùgbọ́n bí ẹ bá ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé ẹ ń pẹ̀gàn Olódùmarè ẹ dàbí iṣẹ́ ọwọ́ gbẹ́nàgbẹ́nà tí ó ní ojú tí kò lè fi ríran, tí ó ní imú tí kò lè fi gbóòórùn, tí ó ní etí tí kò lè gbọ́ràn. Olójúkòkòrò kò lè ní inú-dídùn láé bí ayé kéré bí kò ju èèso akèǹgbè lọ. Ẹ̀yin tí Olódùmarè fún ní ọgbọ́ ti kò lè ó, ẹ̀yin gbọ́ kí kìnnìún wá sí ọdọ Ọlọ́run Ọba ní ọjọ́ kan ki ó wí fún un pé kí ó kọ́ ààfin fún òun nítorí pe òun ni ọba àwọn ẹranko? Ẹ̀yin rí aláǹtakùn kí ó wí pé òun kò ran òwú mọ́? Ẹ̀yin rí àkùkọ kí ó wí pé òun kò ní í kọ? Ẹ kíyè sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, lékèélékèé ń fò láti ibi kan sí ibi kejì lọ́dọọdún, àparò ń wá oùnjẹ rẹ̀ káàkiri inú oko, àdán ń ffi ẹnu jẹun ó tún ń fi ẹnu yàgbọ́, ara ẹyẹ mìíràn dà bí ara aṣọ funfun, òmíràn dà bí aṣọ àrán, omíràn dà bí aṣọ aláró tí wọ́n ti pa tí ó dúdú kẹlẹkẹlẹ. ẹ̀yin kò mọ̀ pé ìyàlẹ́nu ni ìwọ̀nyí! Ẹ máa là kàkà àti lọ síwájú nínú ohun rere gbogbo, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe máa na ọwọ́ sí ohun tí ọwọ́ yín kò lè tó. Bí ọmọdé bá ti bẹ̀rẹ̀ gbé ìwà ojúkòkòrò ni ó ti yẹ kí àwọn òbí rẹ̀ máa bá a wí, kì í ṣe òbí nìkan, bí kò ṣe gbogbo ìbátan pẹ̀lú. Ojúkòkòrò ni ọmọ ìyá ìlara, àti ìlara àti owú jíjẹ ọ̀kan náà ní. Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, ẹ kíyè sí ọ̀nà yín. Mo ń lọ sí ọ̀run lónìí, Ọlọ́run Ọba si tún fún mi ní aṣẹ wí pé kí n fi yín sí ipò yín àtijọ́. Ó dìgbà, láti òní lọ, n kò wá sí ọ̀dọ̀ yín mọ́ ẹ máa ṣe ayé yín lọ, ènìyàn yàtọ̀ sí màlékà, ará ayé yatọ sí ará òde ọ̀run. Báyìí ni Aṣojú-Olódùmarè ṣe tí ó lọ tí kò sì tún padà mọ́, fi eléyìí ṣe àríkọ́gbọ́n, ìwọ Olówó-ayé, ọ̀rẹ́ mi. Báyìí ni Baba onírùngbọ̀n yẹ́úkẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, lẹ́hìn èyí a díde kúrò ní orí ilé rẹ̀, a wá sí ìsàlẹ̀ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì náà á ń gbádùn ara wa. Ilẹ̀ kò ì tí ì ṣú nígbà tí mo ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, nígbà tí ọ̀rẹ́ mi náà sì ronú ohun tí à bá fi dáráyá títí, ò dàmọ̀ràn wí pé kí a lọ dé ilé Àrùn tí í ṣe ìyàwó Ikú ṣùgbọ́n mo kọ̀ fún un: nítorí nígbà tí mo dé ilé ọkọ rẹ̀ ṣáájú eléyìínì ilé náà kò fà mí mọ́ra, kí olúwaarẹ̀ rí Ikú kí ó tún lọ rí Àrùn kì í nǹkan rere. Lẹ́hìn èyí a tún padà gun orí òkè ilé náà lo, nígbà tí a sì dé ọ̀hùn tí a jókòó tán, tí mo jókòó díẹ̀ tí a kò sọ̀rọ̀, mo dìde mo fi ọwọ́ bọ inú àpò ṣòkòtò mi bí ìgbà tí àwọn alákọ̀wé bá ń ṣe fáàrí, nígbà tí mo sì yan sókè tí mo yan sódò tán, mo tún bá ìdí lọ sí orí àga, mo gbé ẹsẹ̀ ọ̀tún mi lé ẹsẹ̀ òsì, mo fi ọwọ́ mi méjèéjì di orúnkún mú, mo fi ẹ̀hìn mi ti dáadáa lórí aga, mo sì wí fún Baba-onírùngbọ̀n wí pé, mo tún ń fẹ́ẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ díẹ̀ sí i lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tí mo wí báyìí tán náà tún bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ í sọ, ó ní: Olówó-ay’;e mi ọ̀wọ́n, onífáàrí ènìyàn ní ọ́, ọkùnrin náà, ó kú ìgbádùn ilé mi yìí o. Olówó-ayé, mo fẹ́ ìtàn kékeré kan fún ọ lónìí mo sì fẹ́ kí o ṣe àkíyèsí ìtàn náà bóyá o lè rí ọgbọ́n kan tàbí méjì fà yọ nínú rẹ̀. Ó ṣe, nígbà kan ni, ọba kán rán ìyàwó rẹ̀ kí ó lọ se ọbẹ fún òun. Kò pẹ́ lẹ́hìn èyí ni ìyàwó náà kó ẹja tútù mẹ́ta wá sí iwájú ọba yìí - ọ̀kan dúdú, ọ̀kan pupa, ọ̀kan funfun. Èyí tí ó dúdú, ó dúdú gan-an ni, èyí tí ó pupa, ó pupa gan-ni; èyí tí ó funfun, ó funfun gan-an ni. Ẹja yìí jẹ́ ìyàlẹ́nu fún ọba ó sì pàṣẹ fún ìyàwó rẹ̀ kí lọ sè é fún òun, obìnrin náà sì lọ. Kò pẹ́ lẹ́hìn èyí nígbà tí ó padà dé iwájú ọba tí ó ń mí hẹlẹhẹlẹ tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ í sọ tí ó wí pé: Kábíyèsí, mo rí èèmọ̀ lónìí. Bí mo ti ń ṣe ẹja wọn-ọnnì, ǹjẹ́ kí n ro obẹ lórí iná, kábíyèsí, ṣe ni ògiri ilé tí mo ti ń wá oúnjẹ là sí méjì tí mo rí ọmọbìnrin kan pẹ́lú idpa lọ́wọ́ tí ó da ẹja mi nù lórí iná. Èyí tí mo rí mọ rèé o, Kábíyèsí, mo dìgbò lulẹ̀ mo dákú. Ìgbà tí mo jí tí mo wo ọbẹ̀ mi àwọn ẹja wọn-ọnnì ti yípada wọ́n dúdú pẹrẹpẹrẹ. Nígbà tí obìnrin náà parì ọ̀rọ̀ rẹ̀ díde, ó ní, ‘Máa ǹṣó, wáá lọ fi àwọn ẹja náà hàn mí’, àwọn méjèéjì sì jùmọ̀ ń lọ. Nígbà tí wọ́n dé inu ilé oúnjẹ, ọba rí i pé lóòótọ́ ni àwọn ẹja wọn-ọnnì ti yípadà tí wọn dúdí bí ìdí ikòkò ọbẹ̀, ìyàlẹ́nu sì ni eléyìí jẹ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá rí wọn. Nítorí ìdí èyí ọba yára ránńṣẹ́ sí ọkùnrin apẹja náà wí pé kí ó lọ pa irú ẹja mẹ́ta bẹ́ẹ̀ wá fún òun. Láìpẹ́ ọkùnrin yìí mú ẹja mẹ́ta tí ó rí bíi tí ìṣáájú wá, ọba sì bá ìyàwó rẹ̀ lọ sí ilé oúnjẹ; nígbà tí ó dá ọ̀hún ó ní kí ìyàwó òun bẹ̀rẹ̀ sí se ọbẹ náà lójú òun. Bí obìnrin yìí tí ń se ọbẹ̀ tí ọba dé adé gòǹgò sí ìddí ìṣaasùn ọbẹ̀ tí ọbẹ̀ sì ń hó ni obìnrin náà bá mú ṣíbí ó ń ọbẹ̀ yìí, ṣùgbọ́n bí ṣíbí tí kan ẹja wọn-ọnnì ṣe ni ògiri ilé náà là sí méjì, dípò ọmọbìnrin tí ó yọ jáde ní ìṣáa’jkú ọkùnrin géńdé kan báyìí ló jáde ti òun ti idà lọ́wọ́ tí ó yí ọdẹ̀ lu iná. Ọba dìgbòlulẹ̀ adé ọba ṣí ó ta fiiri síwájú, ọba dákú, ìyàwó dákú, àwọn ìránńṣẹ́ tí ó tẹ̀lé ọba dákú, ìgbà tí atẹ́gùn sì tóó fẹ́ sí wọn ni wọ́n tóó jí. Ìwọ ọ̀rẹ́ mi, o kò rí i pé nǹkan tí ó gbé aya lulẹ̀ tí ó tún gbé ọkọ lulẹ̀ kúrò ní nǹkan yẹpẹrẹ? Nígbà tí ọba dìde tí ó lọ sí inú àa[fin lọ́hùn-ún tí ó simi tán ó ránńṣẹ́ sí ọkùnrin apẹja yìí ó sì tún wí fún un kí ó bá òun wá ẹja mẹ́ta sí i. Onítọ̀hún tún lọ ó lọ wá abàmì ẹja wọ̀nyí wá. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ọkùnrin yìí fi ń lọ nítorí ìgbà-kígbà tí ó bá ti mú ẹja wọ̀nyí wá, owó geregere ni ọba ń san fún un. Kí ọkùnrin náà tóó mú ẹja tí ọba rán an dé, ọba ti ránńṣẹ́ sí àwọn ìjòy[r rẹ̀ wí pé kí wọ́n wá sí aafin òun. Nígbà tí wọ́n dé, ó kó gbogbo ohun tí ojú rẹ̀ rí ó rò ó fún wọn ó sì tún wí fún wọn pẹ̀lú pé òun ń fẹ́ kí nǹkan náà ṣẹlẹ̀ lójú gbogbo wọn. Àwọn ìjòyé wọ̀nyí dúpẹ̀ lọ́wọ́ ọba wọn wọ́nj sì fi ohùn kan wí bàyìí pé, Aláṣẹ, èkejì òrìṣà, a dúpẹ́, a óò dúró kí ọ̀ràn ṣe ojú wa. Láìpẹ́ ìyàwó ọba náà wáá sọ fún ọba kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé ọkùnrin apẹja náà ti mú ẹja dé ọba sì pàṣẹ kí wọn mú un wá sí iwájú òun, ó ní Ọmọkùnrin, ọ̀rọ̀ èmi àti ìwọ kúrò ní ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀, mú ẹja wá kí á máa se ẹja. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í se ẹja yìí bí ó sì tún ti tó àkókò àti ro ọbẹ̀ tí ìjòyè kan mú ṣíbí tí ó ń ro ọbẹ̀ ṣe ni ògiri ilé náà tún là sí méjì tí ọkùnrin ńlá méje jáde ti àwọn ti idà olójú méjì lọ́wọ́, ti wọ́n tún da ẹja lu iná – ìjàngbọ̀n dé, ìjòyè ń kọlu ìjòyè, ayaba ń kọlu ayaba, ọba fo ojú fèrèsé jáde, ṣe ni ẹ̀wù agbádá ọba ń fẹ́ lẹlẹ níbi tí ó tí ń sálọ. Lẹ́hìn ìgbà tí ojú ọba rọ̀ tán ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ láti wá ìddí àwọn ẹja yìí, ẹja tí ó jẹ́ pé ènìyàn kò gbọdọ̀ sè afi bí olúwaarẹ̀ múra sílẹ̀ àti máa sáré ìje, ọba wí fún ọkùnrin apẹja náà pé kí ó múra ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ki ó mú òun àti àwọn ìjòyè òun lọ sí odò tí ó ti ń pá àwọn ẹja wọn-ọnnì wá. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, tí àwọn ìjòyè pé sí inú ààfin tí wọ́n múra àti lọ sí odò náà ọkùnrin náà kò gbogbo wọn, ó ń kó wọn lọ. Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún gbogbo ènìyàn pé wọn kò rìn ju wákàtí mẹ́ta lọ nígbà tí wọ́n dé odò abàmì náà bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò sí rí odò náà rí níbi tí wọ́n gbé bá a. Nígbà tí wọ́n rìn síwá wọ́n rìn i pé adágún odò ní. Wọ́n rin etí odò yìí wò, wọ́n rìn síwá wọ́n rìn sẹ̀hìn bẹ́ẹ̀ ni odò náà mọ́lẹ̀ bí i dígí, gbaǹgba ni wọ́n sí ń wo àwọn ẹja wọn-ọnnì bí wọn ti ń tẹ̀lé ara wọn káàkiri inú omi. Ṣùgbọ́n bí odò yìí ti ṣe rìn tí ó ibẹ̀, àti bí ẹja inú rẹ̀ ti ṣe yàtọ̀ sí àwọn ẹja mìíràn, ọ̀ràn yìí ta òye gbogbo ènìyàn yọ. Nígbà tí ó ṣe, ilẹ̀ ṣú, gbogbo àwọn ènìyàn wọn-ọnnì si ṣe ibùsùn sí etí adágún odò yìí, wọ́n sùnlọ. Òṣùpá dà bí ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni bí wọ́n ti sùnlọ wọn-ọnnì, ọba kò lè sùn rárá, ó ń ytí gbiri káà kiri orí ibùsùn nítorí ìtumọ̀ adágùn odò yìí kò yé e. Ní ìkẹhìn nígbà tí ara rẹ̀ kò gbà á mọ́, ó díde ó jí igbí kejì rẹ̀, ó wí fún un pé òun ń wádìí odò náà lọ, àti pé bí ilẹ̀ bá mọ́ tí òun kò bá sì tí ì dé, kí igbá kejì òun wí fún àwọn ènìyàn pé ó ṣe òun bí àárẹ̀ àti pé òun sùn sí inú ilé kékeré tí òun yára kọ́ sí etí odò náà ni. Lẹ́hìn tí ọba tí ṣe étò tán, ó fi orí lé inú igbó, òun nìkan àti Ọlọ́run Ọba, ó ń yí inú igbó kiri. Nígbà tí ó pẹ́ tí ọba yìí tí ń rìn káàkiri nínú òṣùpá báyìí ni ó déédéé rí ilé ńlá kan nínú èyí tí wọ́n tan iná sí. Ilé yìí dára púpọ̀, ó dárá ju ààfin ọba pàápàá lọ. Ìlẹ̀kùn ilè náà ṣí sílẹ̀ ó sì wọ inú rẹ̀ lọ. Nígbà tí ó dé ọ̀hún tán ó ń wò káàkiri bóyá óun lè rí ènìyàn nínú rẹ̀, ibi tí ó sì tí ń ṣe èyí ni ó ti bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ igbe ẹni kan nínú ìyàrá kan báyìí, ó ń sọkún. Nígbà tí ó dé ibi tí ó ti ń gbọ́ igbe yìí ó rí ọkùnrin arẹwà kan tí ó jókòó lé orí àga. Ó ki ọkùnrin náà ó sì ṣe ìbéèrè, ó ní, pẹ̀lẹ́ o, kí ló kúkú dé tó bẹ́ẹ̀ tí o fi ń sọkùn? – ìwọ àgbàlagbà? Ọkùnrin náà sì dá a lóhùn, ó ní, bẹ́ẹ̀ ni, bí ó bá mo bí ọ̀rọ̀ mi ti rí, o kò bá tí sọ bẹ́ẹ̀. Ọba yìí sì tún fún un lésì, ó ní, Jọ̀wọ́ má ṣàìjẹ́ kí n mọ nǹkan tí ń ṣe ó, nítorí a kì í mọ̀, Ọlọ́run lè ní kí n tó ẹni tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ. Lẹ́hìn èyí ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ mú ìtàn ara rẹ̀ ó ń sọ ọ́, ó ní: ju ẹ̀sín fún mi. Ọba ni mo ti jẹ́ tẹ́lẹ̀ rí mo sì ní ìyàwó kan ti mo gbọ́ kẹ̀lé dé góńgó, àṣé ògbálógbòó àjẹ́ ni. Ìgbà tí ó bá di alẹ̀ tí mo bá jẹun tán a fi oògùn burúkú sí inú omi tí mo máa mu bẹ́ẹ̀ ni n kò sì nì í mọ nǹkan kan ní tèmi. Oògùn yìí wà wí pé kí n baà lè tètè sùn lálẹ́ àti wí pé bí mo bá sùn tán kí n má baà jí títí ilẹ̀ yóó fi mọ́ tí òun tìkaraarẹ̀ yóò jí mi. Ó ṣe ìwọ̀nyí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láìjẹ́ pé mo mọ nǹkankan. Kí Olódùmarè gba ni lọ́wọ́ àgbàbàgebè obìnrin, ẹnu àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ dùn ju oyin ìrèké wọ́n sì lè tọ́jú ọkùnrin ju ẹnikẹ́ni nínú ayé lọ, orúnkún wọn kò jìnà sì ilẹ̀, wọ́n lọ kúnlẹ̀ ní ìgbà ẹgbàágbèje lọ́jọ́ kan. Obìnrin burúkú náà tàn mí jẹ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà kí ó tóó di pé Olódùmarè tú àṣírí rẹ̀ sí ìta, báyìí ni: Nígbà tí mo sùn sílẹ̀ ní ọjọ́ kan tí mo di ojú mi láìjẹ́ pé mo sùnlọ, nǹkankan ṣẹlẹ̀. Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mi méjì ń sọ̀rọ̀ sí ara wọn. Ọ̀kan dáhùn, ó ní, Ó mà ṣe o, ọkùnrin yìí kò lè fura ní ọjọ́ kan láée wí pé oògùn ni ìyàwó òun ń fi sí omi fún òun mu ni alaalẹ́! Èkejì sì dáhùn, ó ní ‘Ó yà mí lẹ́nu ṣùgbọ́n oògùn náà mà kúkú lágbára o, bí ó bá ti fi í fún ọ̀gá wa, wéré ọ̀gá a sùn kò sì ní i jí àfi bí obìnrin náà bá tìkaraarẹ̀ jí i.’ Èyí èkínní sì tún dáhùn, ó ní, Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbà tí ọ̀gá tóó sùn tán lánàá ni obìnrin náà tó jáde lọ, àkùkọ sì kọ kí ó tóó dé ní òwúrọ̀ yìí. Báyìí ni àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ si sọ láìmọ̀ pè gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ bẹ ni àtẹ́lẹwọ́ mi. Ara sì bẹ̀rẹ̀ sí ta mí pàrà. Nígbà tí ó tó àkókò àti sùn mo bọ́ sí orí ibùsùn mi wéré mo ti ṣe bí ẹni pé mo sun lọ bẹ́ẹ̀ ni n kò sùn, ṣùgbọ́n ohun tí ó jẹ́ kí n lé ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé nígbà tí mo máa jẹun alẹ́ ọjọ́ náà n kò mu omi tí obìnrin náà fún mi, mo dà á nù ní ibi ojú fèrèsé mi láì jẹ́ pé ó pé mo ṣe bẹ́ẹ̀. Bí mo ti bọ́ sí orí ibùsùn ní alẹ́ ọjọ́ tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí tán ni ìyàwó mi pa iná tí ń bẹ nínú iyàrá mi, ó dìde ó jẹ ataare kan lẹ́nu ó sì tu ú sí mmi lára, ó ní, ‘Bí igi àjà bá sùn kì í dìde, alákọrí rẹ kò gbọdọ̀ dìde títí n ó fi dé. Nígbà tí ó wí báyìí tán ó kọjú sí ọ̀nà ó ń lọ, èmi náà yára dìde mo fa àdá mi yọ mo rọra ń tẹ̀lé e lọ. Èyí tí ó yà mi lẹ́nu jùlọ ni pé ṣe ni gbogbo ìlẹ̀kùn tí ó wà ní ojú ọ̀nà bẹ̀rẹ̀ sí ṣí lọ bí ó ti ń kọjá láìjẹ́ pé ó fi kọ́kọ́rọ́ sí wọn, ṣùgbọ́n bí òun tí ń lọ bẹ́ẹ̀ náà ni èmi náà ń tẹ̀lé e lọ. Nígbà tí ó ṣe, ó já sí gbangba ìta, èmi sì tẹ̀lé e, lẹ́hìn èyí ó kúrò ni ààrin ìlú pátápátá èmi náà tún ń bá a lọ, nígbà tí ó pẹ́ ó yà sí ọ̀nà kan báyìí, èmi náà sì yà tì í, nígbà tí ó rìn ọ̀nà yìí jínnà ó dé gbangbakan níbi tí ó tẹ́jú púpọ̀. Nígbà tí ó dá ibẹ̀ ó bá ọkùnrin kan tí ó ti dúró sí ibẹ̀ dè é, ọkùnrin náà wọ ẹ̀wù títóbi ńlá kan, ẹ̀wù agbádá funfun tí àwọn oníṣọ̀nà ti ṣe ẹwà sí lára tí ó rí jìngìnnìjinginni. Nígbà tí ìyàwó mi yọ sí i ó bẹ̀rẹ̀ sí bínú, ó ní, Ó ti pẹ́ jù lónìí, ìgbà tí o mọ̀ pé o kò lé wá kí ní ṣe tí o kò sọ bẹ́ẹ̀ lánàá, n kò fẹ́ kí ènìyàn máa fi mi ṣe fáàrì tí kò níláárí kan rárá, o kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ láéláé o.’ Nígbà tí ó wí báyìí tán ìyàwó mi kúnlẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ ó ní kí ó má ṣe bínú, pé n kò tètè sùn ni, ó dì mọ́ ọkùnrin yìí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu. Nígbà tí ó ṣe wọ́n dá ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀ ìyàwó mi si bẹ̀rẹ̀ sí tú gbogbo àṣírí tí mo fi lè e lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́nm sì bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi í sọ ti èkínní ń bú mi tí èkejì ń bú mi tí wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ mi dárayá tí wọ́n ń sọ ọ́ ní ìsọ ẹ̀gàn tí wọ́n sí ń pè mí ní orúkọ tí bàbá àti ìyá mí kò sọ mí, inú bí mi, mo fa àdá yọ mo bọ́ ssí ààrin wọn bí ìmọ̀nàmọ̀nà mo ṣá ọkùnrin yìí ó ṣubú lulẹ̀, ìyàwó mi sá lọ ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé emi ni. Lẹ́hìn èyí mo kúrò ní ibẹ̀ mo wá sí ilé mo bọ́ sí orí ibùsùn mi mo sùn lọ. Lẹ́hìn èyí ìyàwó mi padà dé òun náà sì gun orí ibùsùn ó sùn tì mí. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ n kò ṣe bí ẹni pé mo mọ nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ìyàwó mi yìí lò sì kọ́ kí mi, ó kúnlẹ̀ ó fi orí balẹ̀ dáadáa, nígbà tí ó sì ń fẹ́ẹ́ fi ẹnu rẹ̀ kò mi lẹ́nu, ẹnu burúkú tí ó ti fi ń ko baba alágbádá lẹ́nu lóru àná, mo gbé ẹnu mi sí ibòmíràn mo wí fún un pé ẹnu ń dùn mí. Nígbà tí ó tó àkókò àti jẹun òwúrọ̀, mo jẹun, bí mo sì ti jẹun tán tí mo jókòó lórí àga mi kan báyìí ni ìyàwó mi dé tí ó kúnlẹ̀ níwájú mi, ó dáhùn ó sì wí pé: Kábíyèsí aláṣẹ, èkejì òrìṣà, àtàrí àjànàkú tí kì í ṣe ẹrù ọmọdé, baba tí ó ju baba ẹlòmíràn lọ, olórí ìlú, baba ijòyè, ọ̀kánlàwọ́n ọkùnrin, ènìyàn pàtàkì láàrin àwọn ènìyàn pàtàkì, ẹni títóbi láàárin àwọn ẹni tí ó tóbi; ojúlówó ọmọlúwàbí, ọkùnrin jáde inú àwọn ènìyàn ń dùn, baálé mi tòótọ́, fọ́rífọ́rí ni mo ń fi yín ṣe. Kábíyèsí, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, mo dúpẹ́ gidigidi, mo dúpẹ́ fún ìtọ́jú yín lórí mi, bí mo bá ti rí yín kò sí ẹni tí ó tún dára lójú mi nínú ayé yìí mọ́, ẹ̀yin ni òrìṣà mi, kí Olódùmarè sì jẹ́ kí á jèrè ara wa. Kí n má fa ọ̀reọ̀ mi gùn lọ, baálé mi, mo ní nǹkan pàtàkì láti tọrọ lọ́wọ́ yín. Ẹ̀gbọ́n mi kan ti ó ti lọ sí ìdálẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ní ìjẹta, ǹjẹ́ kí n lọ wò ó lánàá, n kì rí àyè rárá, gbogbo àwọn àlejò tí ó wá’kí yín lánàá kò jẹ́ kí n rí àyè lọ, àfi ìgbà tí ó di òwúrọ̀ lónìí tí mo déédéé rí oniṣẹ pé ẹ̀gbọ́n mi náà tí ṣe aláìsí. Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ohun ẹ̀dùn púpọ̀ fún mi, Kábíyèsí - ẹni tí n kò ì tí ì fi ojú kàn láti ọdún mẹ́ta! Kí ó sì wáá jẹ́ pé òkú rẹ̀ ni mo máa rí! eléyìí jẹ́ ohun ẹdùn fún mi. Nísisìyí, nǹkan tí mo sì fẹ́ẹ́ tọrọ lọ́wọ́ yín báyìí ni pé kí ẹ fún mi láyè nínú àa[fin yìí kí n ṣe ibojì ẹ̀gbọ́n mi yìí sí ibẹ̀, kí n sì máa fi ojú wo ibojì náà báyìí, nítorí ọ̀rọ̀ náà ká mi lára púpọ̀. Kábíyèsí, kí Ọọ́run bùn yín lẹ́miìí o. Báyìí ni ìyàwó mi náà sọ. ẹni tí ó jẹ́ olórí àwọn ayaba. Ṣùgbọ́n n kò tilẹ̀ ni èrò rárá pé ọkùnrin tí mo rí pẹ̀lú rẹ̀ nínú òṣùpá ni ó ń pè ni ẹ̀gbọ́n fún mi. Nítorí náà mo fún un ní àyè kí ó lọ gbé òkú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ náà wá, mo sì fún un ní díẹ̀ nínú àwọn ìrán\nṣẹ́ mi pé kí wọ́n bá alọ, gbogbo wọn sì lọ. Nígbà tí obìnrin náà padà dé tí ó gbé òkú náà dé ààfin tí mo wò ó, o di ọkùnrin tí mo rí pllú ìyàwó mi ni ọ̀gànjọ́ òru tí wọ́n ń fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu – kí Olódùmarè gba ni lọ́wọ́ àwọn ayédèrú ènìyàn tí àwọn ọmọ ayé ìwòyí ń fi hàn bí ẹ̀gbọ́n, tí wọ́n ń gbé ga gẹ́gẹ́ bí àbúrò, tí wọ́n ń yẹ́ sí gẹ́gẹ́ bí ìbátan wọn. Èké ni wọ́n, ní ọjọ́ tí okùn àṣírí bá tú, ojúlówo iyèkan kò ní ṣáìfi ojú hàn gbangba. Nígbà tí mo bẹ ojú òkú yìí wò ara rẹ̀ kún fún ẹ̀jẹ̀ gidigidi, mo wọlé mo mú àdá, mo fi í sí abẹ́ aṣọ mo sì ké sí ìyàwó mi; orí àga tí o bá mi yìí náà ni mo jókòó lé, nígbà tí ìyàwó mi dé, ojú rẹ̀ ti yípadà sí tèmi, àṣé ó ti rí gbogbo nǹkan tí mo ń ṣe lẹ́hìn wọn-ọnnì, nítorí àjẹ́ ni. Òun pàápàá ti múra sílẹ̀ dè mí, bí mo sì ti béèrè ti mo bú sí ẹ̀rín tí mo wí pé, ‘O káàbọ̀ o, ṣe àlàáfíà ní ayédèrú ẹ̀gbọ́n rẹ wà? Ṣe ni mo rí i tí o kọjú sí mi tí ó sì da omi kan báyìí lù mí lára, ò ké lóhùn rara, mo sì ta gìrì, ó ní, ‘Mo pa á láṣẹ wí pé kí àyípadà dé bá ìwọ ọkùnrin tí ń fi olùfẹ́ mi ṣe yẹ̀yẹ̀, kí ìwọ yípadà láti ẹsẹ̀dé èkít’[i ìdí sí òkúta, kí ìwọ sì jókòó títí si ibi tí ìwọ wà yìí, títí ọjọ́ tí mo bá tú ọ sílẹ̀. Bí iṣu bá yí padà a dí iyán, bí àgbàdo bá yípadà a di ògi, bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé èmi náà ń bọ̀ wáá jèrè iṣẹ́ ọwọ́ milọ́wọ́ àwọn ogun ọ̀run, síbẹ̀ n kò ní ṣáìlo agbára tí Ẹlẹ́dàá fi fún àwọn ẹ̀dá alááyé lórí ilẹ̀ ayé láti fi ṣe ọ́ ní ibi. Bí ó ti wí báyìí tán ni mo rí i wí pé láti ẹsẹ̀ mi títí dé ìbàdí, kò sí egungun, kò sí ẹran, kò sí iṣan, kò sì sí ẹ̀jẹ̀ mọ́, gbogbo ibẹ̀ ti yípadà ó ti di òkúta n kò sí lágbára lórí rẹ̀ mọ́. Láti ọjọ́ náà ni mo ti wà lójú kan báyìí ti n kò lè yí ara padà mọ́, n kò jẹun bẹ́ẹ̀ ni ebi kò pa mi bẹ́ẹ̀ ni n kò sì kú. Lẹ́hìn tí ó sọ ìtàn yìí tán ọkùnrin náà ká aṣọ sí òkè, nígbà tí ọba yìí wò ó lóòótọ́, láti ìdí títí dé orí nìkan ni ó jẹ́ ara tí ó ní ẹran, egungun àti ẹ̀jẹ̀. Láti ìdí sí apá ìsàlẹ̀ dé àtẹ̀lẹsẹ̀ òkúta pátápátá gbáà ni. Lẹ́hìn èyí ọba náà béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin yìí ibi tí ìyàwó àjẹ́ náà wà ó si dá a lóhùn báyìí pé: Ọ̀rẹ́ mi n kò mọ ibi tí ó wà gan-an, ṣùgbọ́n nǹkan tí mo rí ni pé nígbà tí ó ti yí mi padà sí bi o ti bá mi yìí ni o ti fi àjẹ́ rẹ̀ yí ìlú tí mo jọba lé ló’ri padà tí ó sọ ọ́ di adágún odò tí ìwọ rí lọ́hùn-ún nì. Oríṣi ẹja mẹ́ta tí ó wà nínú odò náà ni oríṣí ènìyàn mẹ́ta tí ó wà ní ilú mi, àwọn kan jẹ́ onígbàgbọ́, àwọn kan jẹ́ onímàle, àwọn kan sì jẹ́ kèfèrí. Láti ọjọ́ tí obìnrin náà ti ṣe báyìí nu ó ti lọ wa ihò kan sí ààrin ilé tí ìwọ wà yìí, ó wa ihò náà ó jìn díẹ̀ ó sì gbé olúfẹ́ rẹ̀ tí mo bẹ́ lórí sínú rẹ̀. Kó wa erúpẹ̀ bo òkú náà ṣùgbọ́n ó dì í ó gbé e sí ibẹ̀ nírètí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ ti òkú náà yóò yípadà tí olúfẹ́ òun yóó díde wáá bá òun. Èyí tí yóó yà ọ́ lẹ́nu jùlọ ni mo fẹ́ẹ́ sọ fún ọ yìí. Lójoojúmọ́ ni obìnrin náà máa ń wá sí ilé yìí ní àfẹ́mọ́júmọ́, ní nǹkan bí agogo márùn-ún òwúrọ̀ a máa gbé ẹrù pàṣán kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́m ìgbà tí ó bá sì dé a bẹ̀rẹ̀ sí fi pàṣán nà mí,ìgbà tí ó bá sì tóó nà mí ní ọgọ́rùn-ún pàṣán ni yóò tóó dákẹ́. Lẹ́hìn ìgbà tí ó bá sì tóó nà mi tán a lọ sí ibi tí òkú olùfẹ́ rẹ̀ wà nínú ihò, nígbà tí ó bá dé ibẹ̀, a sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, a wí pé: Ọ̀rẹ́ mi ayé, ọ̀rẹ́ mi ọ̀run, ọjọ́ wo ni ìwọ ń bọ̀ wáá rí mi? Nítorí rẹ mo pa odidi ìlkú rẹ, nítorí rẹ mo mú ènìyàn kúrò lórí oyè, ọ̀rẹ́ mi ayé, ọ̀rẹ́ mi ọ̀run, ọjọ́ wo ni ìwọ ń bọ̀ wáá bá mi? Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń sọ lójoojúmọ́, nígbà tí ó bá sì nà mí ní pàṣán títí, tí mo kérora títí, a lọ sí ọ̀dọ̀ ayédèrú ẹ̀gbọ́n tí ó ti kú a máa bẹ̀ ẹ́ kí ó ti ọ̀run wáá rí òun. Nígbà tí ọkùnrin náà sọ báyìí tán, inú ọba tí ó ń sọ̀rọ̀ fún bàjẹ́. Lọ́nà kínní, inú rẹ̀ bàjẹ́ láti gbọ́ ìyà burúkú tí ọkùnrin náà ń jẹ lójú kan yìí, lọ́nà kejì, inú rẹ̀ dùn nítorí pé ó rí nǹkan tí ó ń wá, o rí ìdí adágún odò, ó mọ ìtumọ̀ oríṣi ẹja mẹ́ta. Ó ṣe ìbéèrè lọ́wọ́ ọkùnrin náà ó sì wí báyìí pé: Ọ̀rẹ́, ńjẹ́ obìnrin náà ń bọ̀ láfẹ̀mọ́jú òní? Ọkùnrin náà sì dáhùn, ó ní, Dandan ni. Lẹ́hìn èyí ọba yìí wáá lo ọgbọ́n kan, ó mú ìbọn rẹ̀ kékeré ó fi i sínú àpò ṣòkòkò rẹ̀ ó lọ sí inú ibojì olùfẹ́ obìnrin náà tí ń bẹ nínú ààfin. Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó wò bí wọ́n ti ṣe di òkú náà dáradára, lẹ́hìn èyí, ó tú u, ó sì kó egungun tí ó bá, ó sọ ọ́ nù lẹ́hìn náà wàyí, ó rọra fi aṣọ náà di ara rẹ̀. Kò dì i le púpọ̀. Ó rọra fi ọwọ́ ọ̀tún mú ìbọn rẹ̀ ó dákẹ́ jẹ́jẹ́ ó ń wo ojú ayé. Lóòótọ́, nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú, obìnrin náà dé ó sì kó pàṣán bo ọkọ rẹ̀ ó nà án títí ó fi pé ọgọ́rùn-ún pàṣán. Ọkọ yìí sọkún gbígbóná, ó mí ìmí ẹ̀dùn, ó bẹ̀bẹ̀ títí, síbẹ̀ obìnrin náà kò dá ọwọ́ nínà dúró, ó gbnàgbé Ọlọ́run Ọba. Nígbà tí ó na ọkọ rẹ̀ tán, ó wá sí ibojì olùfẹ́ rẹ̀ yìí ó ké bí í tí í máa ké wí pé, Ọ̀rẹ́ mi ayé, ọ̀rẹ́ mi ọ̀run, ọjọ́ wo ni ìwọ ń bọ̀ wáá rí mi? Nítorí rẹ mo pa odidi ìlú rẹ́, nítorí rẹ mo mu ènìyàn kúrò lórí oyè, ọ̀rẹ́ mi ayé, ọ̀rẹ́ mi ọ̀run, ọjọ́ wo ni ìwọ ń bọ̀ wáá rí mi? Nígbà tí ó wí báyìí tán, ọba tí ó wà nínú ihò dá a lóhùn, ó ní, Ọ̀rẹ́ mi ayé, ọ̀rẹ́ mi ọ̀run, mo ń bẹ ní ibodè ọ̀run o. Oníbodè kò ṣí ìlẹ̀kùn, ó pa ìlẹ̀kùn ọ̀run dé mọ́ mi o. Bí o bá ń fẹ́ kí n máa bọ̀ lọ yí ọkọ r��� padà sí ipò ènìyàn kí ó dà bí tí àtẹ́hhìnwá, oníbodè yóò ṣí ìlẹ̀kùn n ó sì wáá rí ọ. Nígbà tí ó dáhùn báyìí inú obìnrin yìí dùn tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ wí pé ibi tí ó ti ń sáré lọ mú oògun tí yòó fi yí ọkọ rẹ̀ padà, gèlè rẹ̀ bọ́ sọnù, aṣọ rẹ̀ tú, yẹ̀rì ló kù sí ìdí rẹ̀ tí ó fi ń sáré lọ. Nígbà tí ó mú omi ó fi oògùn sí i ó lọ́ sí ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀ ó dà á lù ú, ó ní Mo pa á laṣẹ fún ọ pé kí o ddìde kí o máa rìn kiri, orí kòo lè wúwo kí ó pa ọrùn lẹ́rù, ara kì í wúwo kí alárá má lè gbé e. Bí ó ti wí báyìí ni ẹsẹ̀ tí ó ti jẹ́ òkúta yíi padà sí ara ènìyàn tí ọkùnrin yìí sì dìde. Nígbà tí ó ṣe èyí tán, obbìnrin náà padà wá sí ibojì olùfẹ́ rẹ̀ yìí, ó ké sí i, ó ní, Ẹni tí m,o fẹ́ràn ju gbogbo ènìyàn lọ, mo tí parí iṣẹ́ tí o rán mi o. Ọba tí ó wà nínú ihò náà sì tún fèsí, ó ní, Iṣẹ́ kan péré lo kù fún ọ láti ṣe. Lọ, yí adágùn omi nì padà sí ilú, yí ẹeja ibẹ̀ padà sí ènìyàn, lẹ́hìn èyí n óò jáde wá gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ìlú náà, ìwọ ni yóò jẹ́ olóró àwọn ayaba, ìwọ yóó máa dé adé owó ìwọ yóó sì máa wọ ẹ̀wù ìlẹ̀kẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ìránṣẹ́ kùnrin àti ìráńṣẹ́bìnrin yóó maa wọlé tí wọn ó sì máa jáde níwájú rẹ. Ìgbà tí obìnrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí ó sáré ó lọ ṣe oògùn rẹ̀, wéré àyípadà dé, adágún omi di ìlú, àwọn ẹja sì di ènìyàn wọ́n ń ta ọjà wọ́n sì ń ra ọjà, wọ́n ń wọlé wọ́n sì ń jáde. Lẹ́hìn èyí ó tún padà tọ ọba nì tí ó ṣe bí olùfẹ́ òun. Nígbà tí ó dé etí ihò ó dáhùn, ó ní, Oùfẹ́ mi, mo ti ṣee bí o ti wí o, máa bọ̀ ìwọ tí í ṣe olúwa mi. Nígbà yìí ni ọba náà wáá dá a lóhùn, ó ní, M dé o, mo ti ọ̀run dé o, olùfẹ́ mi pàtàkì, máa bọ́ nínú ihò kí ó wáá fà mí lọ́wọ́ dìde. Inú obìnrin yìí dùn sí ọ̀rọ̀ tí ó gbọ́ yìí, ó mú aṣọ rẹ̀, ó ró o dáadáa, ó fún gèlè rẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́, ó ń lọ sí inú ihò látti lọ pàdé ẹni tí ó ṣe bí í ṣe olùfẹ́ òun. Ọba tí ó wá nínú ibojì tún ìbọn rẹ̀ ṣe dáadáa, nígbà tí ó rí i pé ó súnmọ́ òun tán àti wí pé òun rí ara rẹ̀ kedere, ó fi ìbọn se oókan-àyà rẹ̀ ó ṣá a, ìbọn dún, òkú alákọrí dún “gbìì” ní ilẹ̀, ó kú pàtàpàtà, kò tilẹ̀ lè mí ara. Bẹ́ẹ̀ ni olóríburúkú parí tirẹ̀ láyé, òṣùpá ènìyàn búburú wọ òkùnkùn, àṣírí aláìníláàárí tú sí ìta. Èdè náà sì wáá yé gbogbo aráyé wí pé, bí èenìyàn búburú bá ń gbilẹ̀, kí àwọn ẹni rere má ṣe yí ìwà wọn padà nítorí èyínì, ọjọ́ kan ń bọ̀ fún ẹni tí ń hu ìwà ìkà, tí gbogbo ènìyàn yóò fẹ́rẹ̀ máa bá a sọkún. Mo ṣe bí àwọn àgbàlagbà tí wí fún wa ní ijọ́sí wí pé, ọjọ́ gbogbo ni ti olè ọjọ́ kan ni ti onínnǹkan. Báyìí ni ọ̀rẹ́ mi parí ìtàn yìí, ọkùnrin pàtàkì, ọ̀rẹ́ mi tòótọ́ Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́, ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta. ÌPINYÀ PẸ̀LÚ BABA-ONÍRÙNGBỌ̀N-YẸ́ÚKẸ́ Ẹ́NI TÍ Ń GBÉ IBI GEGELE ÒKÚTA Bí Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán ni ìránńṣẹ́ rẹ̀ kan tí ìsàlẹ̀ ilé náà wá, ó wí fún un pé àwọn àlejò dá fún un, gbogbo wa si sọ̀kalẹ̀ láti lọ wo àwọn àlejò náà. Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ nígbà tí a dé ìsàlẹ̀ tán tí a rí i pé àwọn àlejjò náà kì í ṣe méjì tàbí mẹ́ta àti pé wọ́n pọ̀ díẹ̀. Nígbà tí mo kà wọ́n, wọ́n jẹ́ mẹ́rinlélógún. Nígbà tí Baba-onírùngbọ̀n kí wọn tán tí ó béèrè bí wọn ti ṣe rìn tí wọ́n fi dé ibẹ̀ tí wọ́n sì là á yé wí pé àwọn ṣìnà sí inú Igbó Olódùmarè ni, ó tún kí wọn dáadáa ó sì fún wọn ní àyè ní ilé rẹ̀. Nígbà tí wọ́n lọ sí ibi tí ó fún wọn tán èmi náà dìde mo lọ kí wọn. Ìgbà náà ni mo sì tóó wáá ṣe àkíyèsí wí pé púpọ̀ nínú wọn ni mo ti mọ̀ ní ilé, àṣé àwọn náà kò kọ́ wò mí dáadáa nii. Ẹni tí mo kọ́ ṣe àkíyèsí ni ọkùnrin kan báyìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìjàǹbàforítì tí ó jẹ́ ọdẹ aperin. Olókìkí ènìyàn ni ọkùunrin náà, nítorí ìgbà tí ó kọ́ bẹ̀rẹ̀ ọdẹ-ṣíṣe ni ó ti ṣe nǹkan kan tí ó ya gbogbo ènìyàn lẹ́nu ní ìlú wa. Ìjànbáforítì ń ré kọká lọ lọ́jọ́ kan ni ó déédéé rí ọwọ́ ìjà erin nínú odò. Nígbà tí ó rí èyí ó mú ọfà nínú apó rẹ̀ ó fi gún ọwọ́ ìjà náà pẹ̀lú agbára, ọfà sì wọlé sinṣin. Nígbà tí erin yìí mú Ìjàǹbáforítì ó sọ́ ọ́ sí orí igi kan, nígbà tí erin sì tún rí i pè ó wà lórí igi yìí ó hú igi náà, ìgbà tí igi tún máa wó, ó wó lu erin lórí, Ìjàǹbáforítì tún bọ́ sí orí erin, lórí erin yìí náà ló tún ti mú ọfà míràn láti inú apó tí ó tún fi gún un. Ibi tí ẹranko yìí tún ti ń jà Ìjàǹbáforítì yí lulẹ̀ láti òkè ó sì fi ara pa bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò mọo ìwọ̀nyí ní ilé ó sì tó ijọ́ mẹ́ta kí ó tóó lè dìde. Ṣùgbọ́n àsẹ̀hìnwá-àsẹ̀hìnbọ̀ erin náà kú, àti ọjọ́ náà ní gbogbo ènìyàn sì ti ń pè é ní Ìjàǹbáforítì baba erin. Nígbà tí mo wò ó dáadáa tí mo mọ̀ pé òun ni tí òun náà wò mí dáadáa tí ó mọ̀ pé emi ni a kí ara wa tayọ̀tayọ̀, mo ní, Ìjàǹbáforítì baba erin, òun náà sì dá mi lóhùn, ó ní Èmi ọkùnrin ni. Mo sì tún bú ẹ̀rín, mo ni,Ìjàǹbáforítì baba erin, òun náà sì súnmọ́ mi, ó ní, Èmi nìyí lọ́wọ́ rẹ. Ìgbà tí ó sì súnmọ́ mi dáadáa tí ó ń bá mi ṣiré ó fi ọwọ́ tẹ̀ mí ní ikùn, ó ní, Olówó-ayé o mà tilẹ̀ ń yọ ikùn. Èmi náà ni, Èwo la ó ṣe? Ibi tí èmi àti Ìjàǹbáforítì tí ń ṣiré báyìí ni mo ti rí ènìyàn mi kan, orúkọ ẹni tí ń jẹ́ n Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ tí ó jẹ́ àná mi ní ilé, nítorí òun ni ó fẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tí ó jẹ́ iyèkan ìyá mi. Ọlọgbọ́n ènìyàn ni ọkùnrin náà gbogbo wa la si fẹ́ràn rẹ̀ ni ilé wa. Àkókò tí mo fi ń múra Igbó Olódùmarè ni òun náà fi ‘’n ṣe òkú bàbá rẹ̀, orúkọ ẹni tí ń jjẹ́ Ìwàtútù tí ó jẹ́ ènìyàn pàtàkì ní ìlú wa. Gbajúmọ̀ pátápátá gbáàni Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ ó sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin. Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ dára lọ́kùnrin. Lójjú mi gbangba báyìí ni wọ́n ṣe fi ọmọbìnrin méjìlá ta Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ lọ́rẹ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ṣùgbọ́n kò fẹ́ wọn. Ó jẹ́ ẹni tí ó gbọ́n púpọ̀, bí àwọn wúndíá sì ti ń wọlé rẹ̀ lọ́sàn-án tí wọn ń wọ̀ ọ́ lóru kò fẹ́ wọn lẹ̀hìn ìgbà tí ó fẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ̀n mi tí mo ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Òun ní ó máa ń kọrin kan báyìí ń ilé wa pé: Obìnrin kan, ìgbàdùn púpọ̀, Obìnrin méjì, ìjàgbọ̀n méjì; Obìnrin mẹ́ta, ìjàngbọ̀ mẹ́ta; Obìnrin mẹ́rin, ìjàngbọ̀ọn mẹ́rin; Obìnrin márùn-ún, ìjàngbọ̀n márùn-ún; Obìnrin mẹ́fà, ìjàǹgbọ̀n mẹ́fà; Obìnrin méje, ìjàngbọ̀n méje; a’ti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, Nígbà tí èmi àti Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ rí ara wa a dì mọ́ ara wa ni; òun náà sì sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan fún mi. Ibi tí a ti ń yọ ayọ̀ yìí ni mo ti ń wo ọkùnrin kan báyìí tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí rẹ́rìn-ín láti ìgbà tí mo ti dé ọ̀dọ̀ àwọn àlejò wọ̀nyí, nígbà tí mo sì wò ó dára-dára mo rí í pé ẹni tí mo tí mọ̀ ni. Aláìgbọ́n ènìyàn pátápátá gbáà ni, ìwà rẹ̀ sì dà bí ìwà ẹranko, bẹ́ẹ̀ ni ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí ti àgùntàn ìdí rẹ̀ náà sì ni èyí tí gbogbo àwọn ará ìlú wa fi máa ń pè é ní Àgùntàn-ìnàkí, dọ̀ǹgíṣọlá ọkùnrin. Ó jẹ́ ẹnì kan tí kò mọ̀ ju pé kí ó máa rẹ́rìn-ín ṣáá lọ. Kòo jjẹ́ ronú lọ́jọ́ kan, bí ènìyàn bá sí ń hu ìwà òmùgọ̀ ní ìlú wa wọn a máa fi olúwaarẹ̀ wé Àgùntàn-ìnàkí, ẹni tí oríkì rẹ̀ ń jẹ́ dọ̀ǹgíṣọlá ọkùnrin. Àgùntàn-ìnàkí ni ó máa ń wá oúnjẹ fún ìyàwó rẹ̀ ní ilé wọn ìgbà tí ó bá sì gún iyán tán tí ó ro ọkà tán tí ó se ọbẹ tán a gbée e kalẹ̀ níwájú ìyàwó rẹ̀, onítọ̀hún a sì máa bú u wí pé oúnjẹ tí ó wá kò dára tó, a máa pòṣé a sì máa ro ẹjọ́ lé e lórí. Oníbàjẹ́ ènìyàn ni Àgùntàn-ìnàkí, ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn wọn-ọnnì tí wọn kì í mọ ìgbà tí ènìyàn bá ń fi wọ́n ṣiré; bí wọ́n wọ ẹ̀wù bùbá báyìí tí o bá ń pọ́n wọn tí o wí pé dànádóógó sányán ni wọ́n wọ̀ inú wọn a máa dùn sí ọ, bí wọ́n wọ aṣọ tí kòbá wọn mu tí o wí pé aṣọ tiwọn dára ju ti ọba lọ inú wọn a máa dùn sí ọ, bí wọ́n bá sọ̀rọ̀ láàrin ìpàdé wọn a máa ṣe ìbéèrè lemọ́lemọ́ pé, ‘Ǹjẹ́ o kò rí i pé ọ̀rọ̀ tèmi ló dára ju ti àwọn ìyókù lọ? Irú ènìyàn báyìí ni Àgùntàn-ìnàkí jẹ́, nítorí náà nígbà tí mo rí i imú ni mo fi kí i. Ẹnìkan tí mo tún ṣe àkíyèsí pé mo mọ̀ nínú àwọn ènìyàn náà ni babaláwo kan tí orúkọ rẹ́ ń jẹ́ Ewédayépọ̀. Ọkùnrin náà ní egbòogi púpọ̀, gbogbo ènìyàn ló sì mọ̀ ọ́n jákèjádì ìlú wa. Ọjọ́ méje ni ó fi gbé inú ihò ilẹ̀ nígbà tí ó gbé iwin kan ní ìyàwó kí ó tóó di pé wọ́n tún fi ara wọn sílẹ̀. Kò sí ewé náà nínú igbó tí ọkùnrin yìí kò mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò sí egbòogi tí ó ṣe ìpamọ́ fún un. A máa bá igi sọ̀rọ̀, ó gbọ́ èdè ẹranko, ó gbọ́ ti ẹyẹ, ó sì gbọ́ ti ẹja inú omi. Nígbà tí mo rí i mo bẹ̀rẹ̀ sí pè é ní oríkì rẹ̀, mo ní ‘Ewédayépọ̀, oníṣègùn ayé, Ewédayépọ̀, oníṣègùn ọ̀run, pàtàkì nínú àwọn babaláwo, irúnmọlẹ̀ ọkùnrin, Ewédayépọ̀, ó ṣe bi iré bí iré ó di ọkọ gbogbo wọn, ẹni tí ó ṣe bí àwàdà tí ó di baba àǹjànnú, ẹni tí ó fi ṣìgìdì ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀, tí ó fi ońdè ṣe ìbàǹtẹ́, Ewédayépọ̀ ọkùnrin, ìwọ ni baba wọn ìwọ la fi ṣe é, ìwọ ni baba àgbàlagbà, ìwọ la fi ṣe é, ẹni tí ń rìn kọ́ńdúkọ̀ńdú, ẹ̀tẹ́ ni yòó fi rí. Bẹ́ẹ̀ ni mi bẹ̀rẹ̀ sí pé oríkì ọkùnrin náà òun sí ń mi orí ó ń dá mi lójùn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bí mo ti dákẹ́ ṣe ni mo déédéé rí Ewédayépọ̀ tí ó bu oògùn funfun kan láti inú àdó tí ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ra mi lórí, orí mi sí di funfun, bẹ́ẹ̀ ni Ewédayépọ̀ sọ mí di olórí funfun lọ́sàn-án gangan, gbogbo ènìyàn ló sì ń wo àtàrí mi bí wọ́n bá ti ń kí mi. Ṣé bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ oògùn dúdú ni ṣe ìbá bá mi lórí mi; àìròtẹ́lẹ̀ ni mo ń tọrọ ọṣẹ kiri mo sì lò tó oníkọ́bọ̀ kí n tóó kúrò ní olórí funfun. Lẹ́hìn èyí, ẹni tí mo tún ṣe àkíyèsí ni ọkùnrin kan báyìí orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Ìbànújẹ́-ìsàlẹ̀. N kò kí ọkùnrin náà dáadáa nítorí láti ọjọ́ tí mo ti mọ̀ ọ́n n kò rí ẹ̀rín lẹ́nu rẹ̀ rí. ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn wọn-ọnnì ti wọn ti ni ìwà burúkú nì pé kí wọ́n máa fa ojú ro nígbà gbogbo, kò sí ẹni tí ó ń mọ ìgbà tí inú wọ́n bá dùn yàtọ̀ si ìgbà tí kò dùn. Bẹ́ẹ̀ irú ìwà yìí ní ń sọ ni lórúkọ, ó ń sọ àǹfààní ènìyàn nù, a máa sọ ẹni títóbidi ènìyàn kékeré, ọmọlúwàbí tí ó bá rí i pé ìwà irú eléyìí ń di ti òun ní láti yára yàgò fún ìwà náà nítorí àbàwọ́n ni lára ẹni. Nígbà tí mo rí Ìbànújẹ́-ìsàlẹ̀ ojú kékeré ni mo fi wò ó, nígbà tí mo sì máa kí i, mo kí i bí ènìyàn yẹpẹrẹ. Ibi tí mo ti ń wo Ìbànújẹ́-ìsàlẹ̀ ni mo ti rí ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹnì tí mo ti mọ̀ dáadáa. Ọkùnrin náà lè kọrin púpọ̀ ó sì lè sọ̀rọ̀ púpọ̀; òun ni wọn ìbá máa pé ni Olóhùn-un-dùùrù ní ìlú wa. Nígbà tí mo wo apá ibi tí ó wà tí mo rí i, mo pè é mo ní, Ọ̀rẹ́ mi, Ọ̀gbẹ́ni Olóhùn-un-dùùrù, o kú àtijọ́ o. Òun náà sì dáhùn, ó ní, Hòo, Olówó-ayé, èmi nìyí lọ́wọ́ rẹ. Èmi náà sì tún dáhùn, mo ní, Olóhùn-un-dùùrù tí ń kọrin bí ẹyẹ. Òun náà sì tún fèsì, ó ní Olówó-ayé, èmi ni mo wí fún ọ, kò sí nǹkan, koko l’ara ọkùnrin le, ẹ kúu jíjẹ, ẹ kúu mímu, ẹ kú àjẹ-ìbéèrè-ẹni. Lẹ́hìn eléyìí, a tún kí ara wa dáadáa a sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwàdà. Ṣùgbọ́n òun lè sọ̀rọ̀ jù, bí olúwaarẹ̀ ní ki òun dúró ìṣẹ́jú méjì aá’jẹ́ kí ó dúró iṣẹ́jú mẹ́rin; ìgbà tí mo sì dúró títí tí Olóhùn-dùùrù ń fi ọ̀rọ̀ dè mí mọ́lẹ̀, mo ń lọ láì tọrọ gááfárà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn náà. Àṣé bímo ti ń lọ nì, ṣe ni Olóhùn-un-dùùrù ń wo ìpákọ́ mi lọ, àfi ìgbà tí mo déedée gbọ́, tí ẹni náà pòṣé tí ó wí pé: Ẹ kò wo ìpàkọ́ rẹ̀. ìgbà tí mo sì wo ẹ̀hìn mo rí i pé ojú rẹ̀ kò dára sí ìpákọ́ mi, mo ni, O jẹ́ lọ jókòó, ìpàkọ́ onípàkọ́ ni ènìyàn ń wò, wọn kì í wo ìpàkọ́ ara wọn. Ìwọ lè sọ̀rọ̀ jù n kò rí àyè tó bí i tìrẹ wọn-ọnnì, ìba ni nǹkan ń mọ. Àwọn tí ó jẹ pàtàkì tí mo mọ̀ nínú àwọn èrò náà ni mo kà sílẹ̀ yìí. Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ ṣe wọ́n ní àlejò púpọ̀ lálẹ́ ọjọ́ náà, gbogbo wọn ló sì jẹun tí wọn yó bámúbámú. Nígbà tí mo rí àwọn àlejò wọ̀nyí ti pọ̀ tó, tí mo sì wo owó ti Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ ti ń ná fún mi láti ìgbà tí mo ti dé, ẹnu yà mí gidigidi. Bí ọmolúwàbí bá lọ síibi kan bí àlejò ó yẹ kí ó mọ ìgbà tí ó tó àkókò kí ó fi ibẹ̀ sílẹ̀, àwọn aláìmòye ènìyàn kò mọ ìwà wọ̀bìa sí àìdára. Bí onílé bá ti ń náwó púpọ̀ jù ó yẹ kí àlejò máa múra àtilọ. Bí onílé tilẹ̀ ń wí pé kí olúwaarẹ̀ jókòó ó yẹ́ kí olúwaarẹ̀ má wí pé òun ń lọ. Láti ìgbà tí mo ti rí ìnáwó ọ̀rẹ́ mi yìí ni mo ti pinnu àtilọ. Nígbà tí a jẹun alẹ́ tán tí gbogbo wa jókòó sí orí ẹní lọ bẹẹrẹ tí a ń sọ̀rọ̀ nínú òṣùpápẹ̀lú Baba-onírùngbọ̀n, mo dá ọ̀rọ̀ lílọ wa sílẹ̀, mo béèrè lọ́wọ́ Baba-onírùngbọ̀n bóyá ó lè mọ ọ̀nà tí a lè gbà padà dé ilé wa. Nígbà tí mo ssọ báyìí Baba-ońirùngbọ̀n wí fún wa pé tòótọ́ ọ̀nà tí a lè bá dé ilé wà ṣùgbọ́n ó sọ fún wa pẹ̀lú pé ọ̀nà léwu gidigidi. Ó tún tẹnu mọ́ ọn dáadáa pé kí á má ṣe ńi èrò àtilọ rárá nítorí pé bí a bá lọ, kò sí àníàmí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóó ṣègbé sí ọ̀nà láàrin wa. Nígbà tí mo wí fún un kí ó fún wa ní ìmọ̀ọ̀ràn ọ̀nà tí a lè gbà ó wí fún wa wí pé ìmọ̀ràn tí òun lè fún wa ni wí pé kí á jókòó sí ọ̀dọ̀ òun kí á máa ṣiṣẹ́ kí á sì máa jẹun láraiṣẹ́ wa. Lẹ́hìn tí ó wí báyìí tán Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ tún ṣe ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó ní kí ó sọ àwọn ohun tí ó lè jẹ́ ìṣóro lójú ọ̀nà fún wa, ọkùnrin náà sí ka àwọn ìṣòro ojú ọ̀nà sílẹ̀ ó ní a ó kọjá ìlú àwọn ejò níbi tí Òjàláìbínú ti ń ṣe ọba wọn àti pé bí a kò bá ṣọ́ra a lè sọ ẹ̀mí wa nù sí ibẹ̀, lẹ́hìn èyí ó tún sọ fún wa pé a óò dé ibi tí àwọn ọmọbìnrin méje kan wwà tí wọ́n máa ń lé ara wọn kiri títí ọjọ́ ayé wọn àti wí pé bí a bá wo apá ọ̀dọ̀ wọn tí a rí tí wọ́n ń ṣe, bí a fẹ́ bí a kọ̀ a óò máa bá wọn ṣiré náà a kò sì ní í lè kúrò níbẹ̀ láéláé. Ó tún sọ onírúurúu àwọn nǹkan mìíràn tí yóò jẹ́ ìṣòro fún wa; ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn iwin burúkú àti àwọn ẹyẹ àjèjì, àwọn ẹranko ajẹ̀nìyàn àti àwọn kòkòrì olóró. Bẹ́ẹ̀ ni Baba-onírùngbọ̀n ka gbogbo nǹkan búburú wọn-ọnnì sílẹ̀ tí wọ́n lè jẹ́ ìdíwọ́ lójú ọ̀nà bì a bá wí pé dandan à ń lọ. Nígbà tí ó parì ọ̀rọ̀ yìí Ìjànbáforrítì dìde dúró láàrin wa ó bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ í sọ, ó ní: Ẹ̀yin ẹgbẹ́ mi gbogbo, ẹ wò mí dáadáa, èmi, Ìjànbáforítì baba erin. Èmi kò kọ ikú, èmi kò kọ àrùn, èmi kò kọ ibànújẹ́ ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni n kò kọ hílàhílo ààrin òru. Mo bi gbogbo yín lónìí, ènìyàn lè rí nǹkan pàtàkì láìjẹ́ pé ó bá ìṣòro pàtàkì pàdé? Ẹ̀yin rí ẹnì kan kí ó dé ipò ńlá láìjẹ́ pé ó tti ṣe nǹkan ńlá sẹ́hìn? Ẹni tí ó wà nínú ayé tí ó ń rìn pẹ̀lú ìbẹ̀rù kò sí nínú àwọn alààyè, ibá ṣe pé àwọn ènìyàn ńlá ń sọ ohun gbogbo tí wọ́n ti bá pàdé kí wọ́n tóó di ènìyàn ńlá ni, àwọn ẹlòmíràn ìbá máa gbàdúrà kí àwọn kú sí ipò ẹ̀hìn. Nítorí náà, lílọ ni a ó lọ. Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ mi ọ̀wọ́n, mo dúpẹ́ lọ́ọ́ yín fún gbogboìtọ́jú wa tí ẹ ti ṣe sẹ́hìn, Ọlọ́run yóó bú sí àpò yín. Nǹkan tí mo fẹ́ kí ẹ ṣe fún wa nìyí, mo fẹ́ kí ẹ ṣe àpèjúwe ọ̀nà ffún wa dáadáa, nítorí bí Ọlọ́run kò bá kọ ìlérí, ilẹ̀ kò níi í mọ́ bá mi ní ilé yìí lọ́la. Kò sí ẹnì kan tí ènìyàn lè bẹ̀rù àfi Ọlọ́run Ọba. Ikú yá ju ìwọ̀sí ffún gbajúmọ̀; kò yẹ kí ọmọlúwàbí rin ìrìn wọ̀bìà lẹ́sẹ̀; bí a bá lọ sí ìdálẹ̀ ó yẹ kí á kó èrè oko dé ilé, ọ̀ràn dandan nì kí á lọ. Báyìí ni Ìjàǹbáforítì sọ tí gbogbo wa dákẹ́ minimini, bí ó sì ti ń fẹ́ẹ́ bá ìddí lọ sí ilẹ̀, ó tún dìde ó kọjú síwa, ó ní Ẹ̀yin ènìyàn wa, à ń lọ lọ́la, ẹ tẹ̀lé mi, n ó ṣe aṣáájú yín ẹ máa di ẹrù, ẹ ṣe ọkàn yín gírí, a ní ènìyàn pàtàkì láàárin wa. Ọ̀gbẹ́ni Olówó-ayé ń bẹ, ènìyàn pàtàkì ni; Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ náà wà láàárin wa, ènìyàn pàtàkì ni; èmi náà sì nìyí, Ìjànbáforítì baba erin; Ọlọ́run ń bẹ fún wa, à ń lọ. Nígbà tí Ìjàǹbáforítì jókòó lẹ́ẹ̀kejì yìí, èmi náà tún dìde mo kín ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́hìn, ìgbà tí mo sì jókkòó tán Oóhùn-ún-dùùrù dìde òun náà bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ í sọ, ohùn Olóhùn-un-dùùrù sì dún tó bẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé nígbà tí ó jókòó Baba-onírùngbọ̀n wò ó lójú, ó wí pé: ‘Olódùmarè fi iyọ̀ sí ètè rẹ.’ Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wa sọ tí a sì fi ìpinnu sí wí pé kí Baba-onírùngbọ̀n ṣe àpèjúwe ọ̀nà fún wa àti wí pé a ó lọní ọjọ́ kejì lágbára Ọlọ́run. Nígbà tí a ti ṣe ìpinnu báyìí ti Baba-onírùngbọ̀n rí i pé ó dájú pe à ń lọ ó pinnu láti ràn wá lọ́wọ́ dé ibi tí ipá rẹ̀ tó, ó wọlé ó mú fèèrè kan jáde ó sì fi í hàn wá, ó béèrè lọ́wọ́ wa bí a bá rí ẹni tí ó mọ fèèrè í fun nínú wa. Olóhùn-ún-dùùrù sì dá a lóhùn pé òun lè fun fèèrè dáadáa. Lẹ́hìn náà ó fi fèèrè yìí lé Olóhùn-ún-dùùrù lọ́wọ́ ó sì wì fúnun pé bí a bá ti ń súnmọ́ ìlú àwọn ejò kí ó bẹ̀rẹ̀ sí fun ún àti pé nígbà tí àwọn ọlọ́pàá tí ń ṣọ́ ojú ọ̀nà ìlú wọn bá ti gbọ́ fèèrè náà gbogbo wọn ó sùnlọ. Ó wí fún wa pé àwọn ọlọ́pàá ejò wọ̀nyí tí wọ́n ń ṣọ́ ojú ọ̀nà ló butú jùlọ nítorí bí a bá ti lè kọjá wọn ìyọnu wa bùṣe àfi bí a kò bá tẹ̀lé ohun gbogbo tí òun bá ṣo fún wa. Ó wáá tún fún wa ní òfin kan lẹ́hìn èyí wí pé a kò gbọdọ̀ pa ejò kan rárá ní ìlú wọn ó sì tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa létí gbọingbọin. Ó wí fún wa pé wa pé ẹni tí ó bá pa ejò ní ìlú àwọn ejò kò ní ṣáì rí ìjà ejò àti pàápàá pé èèwọ̀ ìlú náà ni. Ò kìlọ̀ ffún wa dáadáa nítorí tí ó wí pé nígbà tí a bá dé ìlú wọn ṣe ni a ó máa rí onírúurú ejò tí wọ́n á máa siré kiri tí wọn ó máa ta ọjà tí wọn ó sí máa ra ọjà lójú wa. Lẹ́hìn náà ni ó sọ̀rọ̀ nípa Òjòlá-ìbínú tí í ṣe ọba ìlú àwọn ejò náà wí pé òun ni ẹ̀dá tí ó burú jùlọ nínú àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti pé kí á ṣọ́ra kí á má ṣe bá àwọn ejò ìlú náà jà kí wọ́n máa baà mú wa lọ sí iwájú ọba burúkú tí ń bẹ ní ìlú wọn. Lẹ́hìn èyí ọkùnrin náà tún gb’é àkèǹgbè títóbi kan fún Ewédayépọ̀, ara alèǹgbè náà dúdú mọnamọna, wọ́n so egungun ejò yí ọrùn rẹ̀ ká, ìyẹ́ onírúurú ẹyẹ ni wọ́n sì fi dí ílẹ́nu. Ọkùnrin náà wí fún Ewédayépọ̀ pé oògùn aporó ní ń bẹ nínú akèǹgbè náà àti wí pé títí á ó fi dé ilé ni kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa mu ìdajì ṣíbí nínú rẹ̀ lójoojúmọ́ àti pé bí a bá ti ń ṣe èyínì kò sí oró ejò tí ó lè mú wa. Ṣùgbọ́n ó tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa létí dáadáa pé agbára ìdajì ṣíbí kan tí a bá mu lóòjọ́ kò ju ọjọ́ kan lọ nítorí náà a kò gbọdọ̀ pa ọjọ́ kan jẹ láì mu egbòogi yìí títí a ó fi dé ilé. Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ ṣe é fún wa púpọ̀. Ó tún fúun wa ní ìgò omi kan ó sì wí fún wa pé bí a bá ri ìṣòro kan lójú ọ̀nà, omi náà yóò jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún wa. Ó sọ fúun wa pẹ̀lú pé omi odò kan tí ó ṣàn la òde ọ̀run já ni, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè rí omi náà bù àfi àwọn ara ọ̀run. Síbẹ̀ Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ rí omi náà bù ṣùgbọ́n kí ó tóó lè bù ú ojú rẹ̀ rí nǹkan, nítorí ó sọ fún wa pé bí kò bà sí ọ̀rẹ́ òun, Ikú, ẹni tí ilé rẹ̀ ń bẹ lágbede méjì ayé òun ọ̀run òun kò bá tí lè rí omi náà bù rárá. Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún wa, nígbà tí ó ń fẹ́ẹ́ lọ bu omi náà, ó yà ẹ̀wù tí àwọn òkú máa ń wọ̀ kí wọ́n tóó lè lo sí òde ọ̀run lọ́wọ́ Ikú eléyìínì náà ló sì wọ̀ kí ó tóó di pé ó lè dé etí odò abàmì yìí tí ó ṣàn la òde ọ̀run kọjá. Ọkùnrin náà sọ fún wa pẹ̀lú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá máa bu omi náà ní òde ọ̀run kò gbọdọ̀ kọ ojú sí i nígbà tí ó bá ń bù ú, kàkà bẹ́ẹ̀ ó níláti kọ ẹ̀hìn síi; ìdí rẹ̀ ni pée ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wo inú omi náà nítorí ẹni tí ó bà wò ó gbangba ni olúwaarẹ̀ yóó maa wo ìtẹ́ Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo àti àwọn alágbára ẹ̀mí tí wọ́n dúró yí ìtẹ́ Olódùmarè ká tí wọ́n ń yin Ẹni tí Ó dá wọn, tí Ó dá ẹlòmíràn, yí Ó dá gbogbo wa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá rí àwọn ẹni mímọ́ tí ó yí ìtẹ́ Olódùmarè ká rí nǹkan, ẹni tí ó bá rí òjììjì Olódùmarè rí ọ̀ràn, ẹni tí ó bá mọ ibùjokòó Ẹlẹ́dàá kò lè mọ nǹkan tí ó máa dé bá òun. Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ wí fún wa pé àjèjì omi ní ń bẹ nínu’igò tí ó fún wa nì àti wí pé kò sí nǹkan tí a kò lè fi í ṣe: bí a bá dà á sí orí ewéko tí a wí pé ewéko náà yípadà kí ó di ènìyàn, yóó di ènìyàn, bá a wí pé kí ó di ẹranko, yóó dí ẹranko nítorí àṣẹe Ọlọ́run ń bẹ lára rẹ̀. Nípa lílò rẹ̀ Baba-onírùngbọ̀n wí báyìí fún wa, ó ní, Nígbà tí ẹ bá ń lo omi yìí, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ epo, ẹ kò gbọddọ̀ jẹ iyọ̀, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ata, ẹ sì níláti wà ní ìhòhò gidigbi bí ẹ ti ṣe wá sí òde ay�� àti bí ẹ ó ti ṣe sí òde ọ̀run. Báyìí ni ọkùunrin náà sa ipá rẹ̀ fún wa, gbogbo wa sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ gidigidi. Ọmọlúwàbí ni Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ ẹni tí ń gbé ibi gegele [[okúta. Ó ṣe ìtọ́jú wa púpọ̀, ó tọ́jú wa gan-an ni. Nígbà tí ó sì di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì tí a máa kúrò ní ilé náà mo fẹ́rẹ̀ sọkùn nítorí n kò rí nǹkan kan tí ǹ bá fún àwọn ọmọ ilé náà. Nígbàq tí mo wo inú àpò mi, tọ́rọ́ péré ni mo rí, ojú sì ń tì mí àti fi eléyìí tọrẹ fún àwọn ọmọ ibẹ̀, ṣùgbọ́n síbẹ̀ náà mo fi tọ́rọ́ yìí fún wọn; nígbà tí mo sì tún wo nínú àpò mi, mo rí àkàrà tí ìyá mi fún mi ní ijọ́sí mo sì bu díẹ̀ fún wọn nínú rẹ̀. Ṣòkòtò mi kan péńpé báyìí tí ó jẹ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ mi ni mo tún fi fún àwọn ìránńṣẹ́ ọ̀rẹ́ mi náà ṣùgbọ́n inú Baba-onírùngbọ̀n kò dùn sí gbogbo aájò tímo ń ṣe wọ̀nyí, gbogbo ìtọ́jú wa tí ó ṣe kò jọ ọ́ lójú, òun jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn wọn-ọnnì tí wọn kì í ṣe oore nítorí kí ènìyàn baà san án padà, ìrétì àwọn ẹni tí ń bẹ lọ́wọ́ Ọlọ́run Ọba. Àwọn tí ó mọ̀ pé asán ni púpọ̀ nínú àwọn ọmọ ènìyàn, bí ẹni tí ń ṣe oore bá sì ní ìrètí wí pé kí àwọn tí òun ń ṣe oore fún mmọ oore nì, olúwaarẹ̀ ń fi ẹ̀hìnti òfuurufú. Mo ṣe bí ìgbà tí ọmọ Olódùmarè pàápàá ṣe oorre fún àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá, ọ̀kan péré ni ó padà wáá dúpẹ́ nínúwọn! Ọmọ aráyé a máa fkláti wa iṣu níbitíwọn kò gbìn iṣu sí, wọn a máa béèrè ọ̀gẹ̀dẹ̀ níbi tí wọn kò tọ́jú ọ̀gẹ̀dẹ̀ sí, àwọn tí kò bá lè fi kọ́bọ̀ tọrẹ wọn a máa fẹ́ kí ẹlòmíràn fisísì fún àwọn. Nítorí náà mo ṣe aájò dé góńgó kí ọ̀rẹ́ mi yìí ba mọ̀ pé mo mọ rírì ohun tí òun ṣe fún mi mo sì yọ̀ láti rí i pé òun náà mo iyì mi nítori nígbà tí pínyà pẹ̀lú ara wa, ẹ̀mí wa kò pìnyá pẹ̀ú ara wọn; a tún ń kọ̀wé sí ara; mo sì ń rí ìwé rẹ̀ gbà títí di òní olónìí, ẹ óò rí dìẹ̀ nínú àwọn ìwé tí a kọ sí ara wa kà níwájú. Nígbà tí a kúrò lọ́dọ̀ Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta, ojú wa rí nǹkan púpọ̀ lójú ọ̀nà, àti eyí tí ẹnu lè sọ àti èyí tí ẹnu kò lè sọ ni a fi ojú wa rí tí a sì ṣe alábàápàdé, bí kò bá sí wí pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba, èmi pàápàá kò bá tí tó ẹni tí ń sọ̀rọ̀ lónìí. Nígbà tí ó di ọ̀sán ọjọ́ kejì tí a kúrò lọ́dọ̀ ọkùnrin náà ní nǹkan déédéé agogo mẹ́ta ni a dé etí ìl’;u àwọn ejò níbi tí Òjòlá-ìbínú tí ń ṣe ọba wọn. Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí á dé ìlú náà a bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ igbé onírúurú àwọn ẹyẹ àti àwọn ọ̀kẹ́rẹ́. Nígbà tí ó si ṣe tí a yọ sí òpópó kan báyìí ni à ń wo ọlọ́pàá àwọn ejò wọn-ọnnì lọ́kàn-ánkán tí wọ́n dúró tí wọ́n ń wo apá ọ̀dọ̀ wa. Ìdí mi di omi, okùn ṣòkòtò mi sì tú. Èyí tí ó yà mí lẹ́nu jùlọ ni pé àwọn ọlọ́pàá náà jọ ènìyàn díẹ̀, bí orí ènìyàn ni orí wọn rí ṣùgbọ́n ara ejò ni ara wọn. Wọ́n ní ẹsẹ̀ méjì-méjì tí ó kúrú tí wọ́n sì fi ń rìn dáradára, ìrù wọn gùn ara wọn sì ní ìpẹ́ tí ó tóbi. Kò sí èyí tí kò tóbi tó géńdé ọkùnrin nínú àwọn ọlọ́pàá wọn-ọnnì, wọ́n ba ni lẹ́ru gidigidi. Bí a ti yọ sí wọn ni Olóhùn-un-dùùrù ti bẹ̀rẹ̀ sí fún fèérè bíó sìti ń fun fèèrè ni a rí i tí gbogbgo wọn sùn lọ a sì kọjá wọn. Ṣùgbọ́n ó dùn mí láti wí pé ibẹ̀ ni Àgùntàn-ìnàkí tí sọ ẹ̀mí ara rẹ̀ nú. Nígbà tí a jí ní òwúrọ̀ ọjọ́a tí á ń lọ sí ìlú àwọn ejò yìí tí a bẹ̀rẹ̀ sí mu oògùn aporó tí Baba-onírùngbọ̀n fún wa Àgùntàn-ìnàkí wí pé oògùn náà korò jù kò sì bá wa mú un lọ́jọ́ náà. Nígbà tí a sì ń sún mọ́ ibi tí àwọn ọlọ́pàá wọn-ọnnì wà ó ní òun fẹ́ẹ́ ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ a sì dúró pé kí ó tètè ṣe tán ìgbà tí kò si tètè ṣetán a múra a ń rìn lọ sí iwájú dè é. Nígbà tí àwa ń rékọjá. Ejá àwọn ọlọ́pàá náà a rí i ó ń bọ̀ ní ìsàlẹ̀ a sì mọ̀ pé àwọn ọlọ́pàá wọ̀nyí kò lè jí lójú oorun títí òun yóó fi ré wọn kọjá. Ṣùgbọ́n nígbà tí Àgùntàn-ìnàkí ń bọ̀ ṣe ni ó bẹ̀rẹ̀ sí pariwo tí ó ń kígbew ńlá tí ohùn rẹ̀ sì gba gbogbo igbó kankan. Nígbà tí igbe yìí pọ̀ jú àwọn ọlọ́pàá ejò jí wọ́n mú un, wéré wọ́n sì bù ú jẹ. Ẹsẹ̀ kan náà ni oró ejò mú ọkùnrin náà, kí á má fa ọ̀rọ̀ gùn lọ bí ilẹ̀ bí ẹni, ibẹ̀ ni Àgùntàn-ìnàkí sá parí ayé tirẹ̀ sí. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe tí a sọ ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn wa nù, Ọ̀gbẹ́ni Àgùntàn-ìnàkí, dọ̀ǹgíṣọlá ọkùnrin; nígbà tí gbogbo wa sì ń sọkún Ìjàǹbáforítì kò sọkùn rárá, dípò bẹ́ẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ sí súfèé ó ń kọrin òwe wí pé, ‘Afọ́jú tí ó di ojú tí ó wí pé òun kò ríran, ìgbà tí kò sùn kí ló rí, aṣeni ṣe ara rẹ̀. Èyìínì ni pé Àgùntàn-ìnàkí ni ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ara rẹ̀. Àgùntàn-ìnàkí ń kọrin kí àwọn ọlọ́pàá ejò baà jí kí wọ́n baà lè da gbogbo wa lójú rú ṣùgbọ́n bí ó ti ń ké ni àwa túbọ̀ ń tẹ ẹsẹ̀ mọ́ ìrìn, ìgbà tí àwọn ọlọ́pàá máa jí wọn kò rí àwa mọ́ ṣùgbọ́n wọ́n rí òun. Títí a fi padà dé ilé bí ọmọ kan bá wí pé òun kì ní í mu oògùn kan, a máa ń pe ọmọ náà ní Àgùntàn-ìnàkí. Nígbà tí a kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá ejò wọn-ọnnì a bẹ̀rẹ̀ sí pàdé ejò lọ́kọ̀ọ̀kan ṣùgbọ́n wọn kò bù wá jẹ, wọ́n lọ ní ti wọn ṣáá ni. Nígbà tí a rìn díẹ̀ a bẹ̀rẹ̀ sí rí ọgbà tíàwọn ejò ṣe gbogbo, nínú èyí tí wọ́n kó àwọn ọ̀pọ̀lọ́ púpọ̀ sí tí wọ́n ń tọ́jú wọn. Bí a ti ń rìn súnmọ́ ni a túbọ̀ ń rí àwọn ọgbà ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí tí àwọn ejò ń sìn bí ewúrẹ́. Ọ̀pọ̀lọ́ ni oúnjẹ wọn òun ni wọ́n sì fi ń ṣe ara wọn ní àlejò. Nínú ọgbà wọ̀nyí mo fi ojú mi gbangba rí ọ̀pọ̀lọ́ tí ó tóbi tó àkúkọ adìẹ̀. Ojú ọ̀nà ìlú àwọn ejò náà ń dán ṣùgbọ́n ìbá dára jù bẹ́ẹ̀ ló níkò ṣe ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọ̀ ara wọn tí ó bọ́ sílẹ̀ tí ó sì dá ìpàǹtí sí ojú ọ̀nà lọ. Ìgbà míràn bí a ti ń lọ, ejò a déédéé já sílẹ̀ ní ìwàjú wa, ìgbà míràn ejò á já kọ́ wa ní èjìká, ìgbà míràn ejò á máa lọ mọ́ wa lẹ́sẹ̀ wọ́n á máa bá wa ṣiré. ÒJÒLA-ÌBÍNÚ TÍ Í ṢE OLÓRÍ EJÒ AYÉ GBOGBO Nígbà tí a yọ sí ìlú wọn gan-an nǹkan kan ṣeẹlẹ̀ sí wa. Nígbà tí ejò kan bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ mọ́ Ìjàǹbáforítì lára kiri ara Ìjàǹbáforítì kọ ìyà yìí nítorí ejò náà bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ̀ rẹ̀ ó sì tọ̀ ọ́ títí dé èjìká. Nígbà tí ó dé èjìka rẹ̀ ó dúró kò sì lọ mọ́. Nígbà tí ó tún ṣe, ejò kejì tún bẹ̀rẹ̀ sí gun Ìjànbáforítì lára eléyìí náà sì tún tọ ara rẹ̀ títí ó fi de èjìká rẹ̀; nígbà tí àwọn ejò, méjèèjì yìí sí rí ara wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣiré ní ọ̀run ọkùnrin náà. Nígbà tí ó pẹ́ tí wọn kò lọ, inú bi Ìjàǹbáforítì: ó mú ṣòkòtò rẹ̀ ó fún un le, ó mú ìbọn rẹ̀ ó tún un ṣe, ó sì kọjù sí wa ó wò wá bí alágbára tí í wo ènìyàn ó bú sí ẹ̀rín, ó ní ‘Ẹni máa kú pàdé ẹni máa pa á, èmi Ìjànbáforítì ọkùnrin, mo gba gbogbo nǹkan, ṣùgbọ́n n kò gba ìwọsí, ènìyàn kì i kú lẹ́ẹ̀mejì, bí ikú bá mú mi n ó maa bá ikú lọ. Bí í ti wí báyìí tán ó mú àwọn ejò méjèéjì ó nà wọ́n mọ́ ilẹ̀, lẹ́hìn eyí ó gbé igi ó nà án mọ́ wọn lórí, ó pa wọ́n, nǹkan dé! Bí Ìjànbáforítì ti ṣe báyìí ni a déédéé gbọ́ agogo kan tí ó lù, kí á sì tóó ṣẹ́ ojú pẹ́ẹ́ àwọn ọlọ́pàá ejò wọn-ọnnì ti sá dé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bu wá jẹ ṣùgbọ́n oró wọn kò ní ipá kan lórí wa nítorí oògùn tí a ti jẹ ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà. Nígbà tí wọ́n rí i pé kò sí nǹkan kan tí ó ṣe wá wọ́n wọ́n mú wa ó di ilé Òjòlá-ìbínú tí í ṣe olórí ejò ayé gbogbo. Háà! Ọlọ́run tóbi lỌ́ba! Nígbà tí a dé iwájú Òjòlá-ìbínú èrò ọkàn mi padà. N kò ní èrò wí pé mo tún lè sí nínú ayé yìí mọ́. Láti ọjọ́ tí mo ti ń rìn kiri n kò í tí ì rí ẹ̀dá tí ó ba ni lẹ́rù bí Òjòlá-ìbínú tí í ṣe olórrí ejjò ayé gbogbo. Òjòlá-ìbínú tóbi púpọ̀, ẹ̀dá afàyàfá ni ṣùgbọ́n orí ènìyàn nió ní àfi wí pé ẹnu rẹ̀ tóbi ju ti ènìyàn lọ. Àgùntàn kò yó Òjòlá-ìbínú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, a máa jẹ tó odidi mààlúù méjì bíó bá ń fẹ́ẹ́ jẹun. Nígbà tí a dé ààfin ọba àwọn ejò yìí a bá a lórí ìtẹ́, o gúnwà gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ sí kájọ yí i káàkiri. Bí ọba náà ti ba ni lẹ́rù tó ni ó lẹ́wà tó, gbogbo ara rrẹ̀ ‘dabì ìgbà tí ogunlọ́gọ̀ òkúta olówó iyebíye bá wọ́ jọ pọ̀ sì ọ̀nà kan; nígb�� tí Òjòlá-ìbínú kájọ tán, ó dàbí òkè kékeré kan. Nígbà tí wọ́n kó wa dé iwájú ọba àwọn ejò, tí òun náà rí wa, inú bí i gidigidi orí rẹ̀ sí yí padà ó túbọ̀ ń tóbi sí i; gbobo àwọn ìjòyè rẹ̀ sí bẹ̀rẹ̀ sí pòṣé wọ́n ń bínú nítorí wa. Nígbà tí Òjòlá-ìbínú bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ í sọ ọ̀nà ọ̀fun rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kù bí òjò,ojú rẹ̀ sì dàbí ìlẹ̀kẹ̀ pupa. Ó ké tìbínútìbbínú ó wí báyìí pé: Ènìyàn! Ènìyàn! Ènìyàn! - Ẹ tún wá mi d’;e ìhín! - Ẹ̀yin ọmọ ènìyàn! Háà! Háà! Háà! Àfi Olọ́run Ọ̀gá Ògo nìkan ló lè parí ìjà tí ó wà láàárin wa: olórró ejò, ọ̀tá ènìyàn, aláìlóró ejò, ọ̀tá ènìyàn, bí ènìyàn rí ejò ní gbangba ènìyàn á pa á; bí ènìyàn rí ejò ní ìkọ̀kọ̀ ènìyàn á pa á; kò sí ọ̀tá tí ó dà bí ọ̀tá tí ó wá láàárin ejò pẹ̀lú ènìyàn àfi ọ̀ta tí ó wà láàárin ọmọ èṣù àti ọmọ Ọlọ́run Ọba. Ẹ mú àwọn wọ̀nyí, ẹ̀yin ọlọ́pàá mi, ẹ kó wọnnlọ sí àgbàlá mi. Ẹ wo èyí tí ó bá sanra nínú wọn, ẹ pa á fún mi; oúnjẹ ni mo máa fi gbogbo wọn ṣe, ìparun ní ń gbẹ̀hìn apànìyàn, àwọn tí ń pa mí lọ́mọ dandan ni kí n máa pa wọ́n lọ́mọ, ọjọ́ kan ń bọ̀ tí ilẹ̀ yóò mọ́ bá àwọn tí ń lépa ọmọnìkejì, níwọ̀n ìgbà tí èmí mi bá wà láàyé, n kò ní í fi ojú rí ọmọ ènìyàn kí ọmọ ènìyàn lọ. Bí ó ti wí báyìí tán ẹ̀dá burúkú náà bú sí ẹ̀rín àwọn ìjòyè rẹ̀ sì fi ohùn ka ké Kábíyèsí, aláṣẹ, èkejì òrìṣà. Ikú tí ń pa ọmọ aláìgbọ́ràn, ìjàgbọ̀n lórí àwọn ọmọ ènìyàn, alágbára lórí àwọn ọmọ olóríkunkun. Kábíyèsí, kábíyèsí, kábíyèsí. Lẹ́hìn èyí wọ́n mú wa lọ sí ẹ̀hìnkùnlé nígbà tí a sì dé ọ̀hún, ènìyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n bí àwa ni a bá, àwọn wọn-ọnnì ti ṣìnà sí igbó ọdẹ wọ́an sì ti bọ́ sí ọwọ́ ọba àwọn ejò náà. Nígbà tí a dé ibi tí wọ́n wà tí a wo apá kan àgbàlá náà báyìí, egungun agbárí ènìyàn tíó wà ní ibẹ̀ ju ẹgbẹ̀rún lọ. Àkókò tí mo ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, ẹ̀rù kò tilẹ̀ tún wáá bà mí mọ́ nítorí ọkan mi ti ń kúrò nínú ayé mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ronú òde ọ̀run. Àwọn ọlọ́pàá wọn-ọnnì to gbogbo àwa tí a ṣẹ̀sẹ̀ dé lẹ́sẹẹsẹ wọ́n sì wo gbogbo wa lọ, wọ́n fi ọwọ́ tẹ̀ wá ní ìdí wọ́n sì wo igbá-àyà wa láti fi mọ̀ bí a ti ní ọ̀rá sí. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ mi wọ́n mú ọkùnrin kan báyìí tí ó dúró tì mí tí ó sanra díẹ̀ jù mí lọ, nígbà tí wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa, wọ́n pa á lójú wa. Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀ lẹ́hìn èyí wọ́n mú oúnjẹ wá fún wa ṣùgbọ́n n kò jẹ oúnjẹ náà nítorí nígbà tí wọ́n ń fẹ́ẹ́ mú oúnjẹ náà wá mo gbọ́ ti wọ́n ń ṣe àríyànjìyàn kan wọ́n ń ṣe àròyè nínú ilé oúnjẹ pé bóyá oògùn tí wọ́n fi sí inú oùnjẹ náà tó láti mú kí á sanra tàbí kò tó. Àwọn ìránńṣẹ́ ọba rọra ń yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sọ̀rọ̀ náà ni ṣùgbọ́n èmi dúró sún mọ́ ògiri ilé oúnjẹ náà mo sì ń gbọ́ ohun tí wọn ń sọ. Àwọn ẹnìk jejì mi jẹ́ oúnjẹ náà ṣùgbọ́n èmi jẹ lára àkàrà tí ìyá mi mú láti isà òkú wá fún mi. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì fi maa mọ́ gbogbo àwọn ti a jọ wà ti yípadà, wọ́n tóbi wọ́n sì sanra. Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ àti Ewédayépọ̀ tí wọn kò ti sanra tó mi ri ti tóbi jù mi lọ. Ìjànbáforítì tí ara rẹ̀ máa ń le koko ti di ẹni ti ara rẹ̀ rọ̀ tí ó sanra tí ó sì ń dán. Nígbà tí mo rí eléyìí mo pe àwọn ẹgbgẹ́ mi sí ìkọ̀kọ̀ mo sì wí fún wọn ohun tí mo ṣe àkíyèsí àti nǹkan tí mo gbọ́, mo sì tún sọ fún wọn pé mo ní àkàrà kan nínú àpò mi tí kò lè tán bí ó ti wù kí á jẹ́ ẹ́ tó àti pé àkàrà náà ni mo rò pé ó yẹ kí á máa jẹ. Nígbà tí ó di ọ̀sán ọjọ́ kejì àwọn ìránńṣẹ́ Òjòlá-ìbínú wá wọ́n tún mú ẹnì kan tí ó sanra nínú wa wọ́n pa á fún ọba wọn. Díẹ̀ ló kù kí wọ́n mu Ìjàǹbáforítì ṣùgbọ́n tí wọ́n yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa wọ́n ní kò sanra tó fún jíjẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún wa ní ounjẹ ní oríṣiríṣi lọ́jọ́ náà ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò jẹ oúnjẹ wọn-ọnnì nínú wa. Nígbà tí ó tán di ọjọ́ kẹta wọ́n mú ẹnì kan nínú wa, ọ̀kan nínú àwọn tí a bá ní ibẹ̀ ni, wọ́n tún pa eléyìínì fún ọba wọn jẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ s�� pa wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan tí mo ń réti ọjọ́ tí ikú yóó kàn mí, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti ń gbé oúnjẹ fun wa tóó nì, b kò jẹ oúnjẹ wọn, àkàrà tí ìyá mi fún mi ni mo ń jẹ òun náà sì ni àwọn ìyókù ẹgbẹ́ mi, àwa tí a jọ kúrò nínú ilé Baba-onírùngbọ̀n ń jẹ, eeléyìí sì ṣe wá ní oore púpọ̀ nítorí kò jẹ́ kí a sanra sí i àti pàápàá a bẹ̀rẹ̀ sí rù níbi tí a ti ń ronú ohun tí a o ṣe. Lẹ́hìn tí wọ́n ti pa púpọ̀ nínú wa tí ó sì jẹ́ pé àwa tí ó kù sílẹ̀ kò pọ̀ mọ́, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí ba ni wí pé nígbẹ̀hìn wọ́n lé wáá mú wa yálà a sanra tàbí a kò sanra. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan báyìí, mo gbé ojú sókè omi bọ́ lójú mi mo ké pe Ọlọ́run, mo ní, Ìwọ Ọlọ́run Ọba, má ṣàìkó wa yọ nínú ìhámọ́ yìí o. Kò sí ohun tí ó ṣòro lọ́wọ́ Ìwọ Ọlọ́run Ọba, kò sí ìbànújẹ́ tí ó dé bá ọmọ ènìyàn tí ìwọ kò lè kó ènìyyàn yọ. Lọ́wọ́ ìbànújẹ́ owó, lọ́wọ́ ìbànújẹ́ ọmọ, lọ́wọ́ ìbànújẹ́ ibi iṣẹ́, lọ́wọ́ ìbànújẹ́ ọ̀tá ilé, lọ́wọ́ ìbànújẹ́ ọ̀tá òde, lọ́wọ́ ìbànújẹ́ ààrin iyèkan, Ìwọ Ọlọ́run yìí nìkan ni Aláfẹ́hìntì ẹni. Gbà mí o. Ọlọ́run, Ọlọ́run gbà mí o; lọ́wọ́ Òjòlá-ìbínú, gbà mí o, Ọlọ́run, Ọlọ́run gbà mí o; lọ́wọ́ ọlọ́pàá ejò, gbà mí o, Ọlọ́run, Ọlọ́run gbà mí o; lọ́wọ́ ìtìmọ́lé ọ̀sán gangan, gbà mí o, Ọlọ́run, Ọlọ́run gbà mí o. Báyìí ni mo bẹ̀rẹ̀ sí wí, àṣé bí mo ti ń sọ̀rọ̀ nì, ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́pàá wọn-ọnnì ń gbọ́ ohun tí mo ń sọ bẹ́ẹ̀ ni ọlọ́pàá yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìrànńṣẹ́ tí ọmọ ènìyàn máa ń bá pádè ní òde ayé tí wọ́n jẹ́ ọ̀lẹ àti àgbàgebè tí í máa fi òfófó wá ojúrere lọ́dọ̀ ọ̀gá wọn kí onítọ̀hún máa baà rí àṣírí wọn. Ọlọ́pàá ejò yìí gbé ọ̀rọ̀ mi lọ sí iwájú Òjòlà-ìbínú, ó ní mo fi í lé Ọlọ́run Ọba lọ́wọ́. Nígbà tí Òjòlà-ìbínú gbọ́ eléyìí ó kígbe ńlá ohùn rẹ̀ sì kù bí òjò, ó ní, ‘Ta ni Ọlọ́run náà tí ó lè gbà yín nínú pàkúté mi, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn! Kí ni Ọlọ́run Ọba jẹ́ níbi tí èmi wà! Lóòótọ́ àwọn irúnmọlẹ̀ wí pé Ọlọ́run ni Ó dá ohun gbogbo ní òde ayé àti òde ọ̀run, ǹjẹ́ bí bẹ́ẹ̀ bá ni, èmi pàápàá ti tóbi nínú ọlá mi, èmi ni olórí àwọn ejò ayé gbogbo. Lọ́la ni ọjọ́ yín mọ ní orí ilẹ̀ ayé, tí agbárí yín yóò dé inú ìṣaasùn ọbẹ̀ mi, bí mo bá ṣáìpa gbogbo yín jẹ́ lọ́la pátápátá, a jẹ́ wí pé bàbá mi kọ́ ló bí mi. Nígbà tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí inú mi bàjẹ́, nígbà tí mo tún rò ọ̀rọ̀ náà wò, inú mi sì dún. Lọ́nà kínnì, inú mi bàjẹ́ láti gbọ́ wíi pé ẹnì kan dá ọjọ́ ikú mi sílẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n lọ́nà kejì mo mọ̀ pé ìparun Òjòlà-ìbínú kò jìnnà mọ́, nítorí ní ọjọ́ tí ẹ̀dá kan bá ti wí pé ti Ọlọ́run kò jámọ́, eléyìíní bẹ̀rẹ̀ ìparun: mo dákẹ́ mo ń wo èyí tí Ọlọ́run máa ṣe. Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀ mo pe àwọn ẹlẹgbẹ́ mi gbogbo jọ mo bi wọ́n kí olúkúlùkù jẹ́ kí n mọ ohun ìjà tí ó wà lọ́wọ́ wọn mo sì wí fún wọn pàtó wí pé ó yẹ kí á ṣe nǹkan kan dandan kí ó tóó di pé ẹ̀dá náà pa wá jẹ. Mo rántí ìjà emi àti Àǹjànnù-ìbẹ̀rù ní ibodè Igbó Olódùmarè mo sì pinnu àti ṣe gudugudu méje. Gbogbo àwọn tí ó jẹ́ pàtàkì nínú wa ni inú wọn dùn sí ìmọ̀rà mi. Olúkúlùkù múra àti ja ìjà díẹ̀ kí á ṣe bí ọkùnrin. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́pàá wọn-ọnnì ti gba ohun ìjà wa gbogbo nígbà tí a ti dé ibẹ̀ wọ́n sì ti kó wọn sínú ilé ìṣúra náà.; Ibi ti a ti ń ronú bí a ti ṣe lè gbà rí àwọn nǹkan wa ni Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ ti wí fún wa pé òun ti ní ọ̀rẹ́ kan láàrin àwọn ìránńṣẹ́ wọn-ọnnì. Àṣé bí àwa ti ń ronú ikú ni Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ ti ń ronú ọ̀nà àtiyọ ó sì ti wá àyè rí àṣsírí ibẹ̀. Òjòlà-ìbínú jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá wọn-ọnnì tí kì í tọ́jú ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn, ìgbà tí ó sì ti di pé àwa kò jẹ oúnjẹ ti wọ́n ń gbé fún wa mọ́ ni Ènìiyàn-se-pẹ̀lẹ́ ti ń fi oúnjẹ wa náà wá ojú rere ọmọ-ọ̀dọ̀ yìí. A kò tilẹ̀ kọ́ mọ nǹkan kan ní tiwa ṣùgbọ́n ohun tí a sáà ń rí ni pé bí wọ́n bá ti ń gbé oúnjẹ bọ̀ Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ ní í máa gbà á lọ́wọ́ wọn a kò sì mọ ibi tí ó ń gbé e lọ àṣé ọmọ -ọ̀dọ̀ náà ni ó ń gbé oúnjẹ yìí fún, wọ́n sì ti ipa bẹ́ẹ̀ si ọ̀rẹ́ ara wọn. Nìgbà tí a pé ọmọ-ọ̀dọ̀ yìí tí mo bu àkàrà díẹ̀ fún un tán, a bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ bá wa kó àwọn nǹkan wa jáde láti inú ilé ìṣúra wá òun náà sì gbà bẹ́ẹ̀ fún wa ṣùgbọ́n ó wí pé ó di ìgbà tí àwọn tí ń sọ ilé ibẹ̀ bá ṣíṣẹ́ ọjọ́ náà parí tí wọ́n kúròi ní áàfin kí òun tóó lè lọ bá wa kó àwọn nǹkan wa. Nígbà tí ó tó déédée agogo márùn-ún alẹ́ àwọn tí ń ṣọ́ ilé náà parí iṣẹ́ wọn wọ́n sì jáde kúrò ní ààfin. Bí wọ́n ti ń kúrò ní ààfin ni ọmọ-ọ̀dọ̀ yìí tí wọ ilé ìṣúra lọ tí ó bá wa kó ẹrù wa. A kó púpọ̀ nínú àwọn oògùn wa fún Ewédayépọ̀ kí ó máa tọ́jú wọn nítorí òun pàápàá jẹ́ babaláwo tí ó fẹ́ràn fáàrí: bí a ba fi ọwọ́ kan àwọn oògùn rẹ̀ a máa halẹ̀ mọ́ wa, ìgbà gbogbo ni òun sì máa ń jẹ ataare lẹ́nu tí ó máa ń dárúkọ Odùduwà, tí ó máa ń sọ̀rọ̀ Àgbọnnìrègún tí ó sì máa ń já ewé inú igbó kiri. Nígbà tí a ti kó nǹkan ìjà wa jọ tán tí a sì kó àwọn oògùn wa pàtàkì fún Ewédayépọ̀ a bẹ̀rẹ̀ sí pa èrò ọ̀nà àtilọ. Kí a tóó lè lọ a níláti pa Òjòlà-ìbínú pàápàá, bẹ́ẹ̀ ni nǹkan ńlá ni eléyìínì. Nígbà tí a ronú ọ̀nà tí a ó gbà tí a kò rí, Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ fún wa ní ìmọ̀ràn kan. Ẹ̀dá afàyàfà ni Òjòlà-ìbínú àyà ni ó si fi máa ń fà lọ wẹ̀ ní àgbàlá lójoojúmọ́. Nǹkan bí agogo mẹ́fà òwúrọ̀ ni ó máa ń lọ wẹ̀ lójoojúmọ́, ìmọ̀ràn Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ ni èyí pé kí á lọ wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdá kí a pọ́n wọn kí wọ́n mú dáadáa, nígbà tí ó bá di alẹ́ kí á lọ ri àwọn àdá náà mọ́ ilẹ̀ kí á kọjú wọn sí ìta, ìgbà Òjòlà-ìbínú bá ń lọ wẹ̀ tí ó bá gbé ẹnu lé àdá, tí àdá náà bá gé e kò ní ṣáì fẹ́ẹ́ tètè sàre kúrò ní ibẹ̀, bí ó bá sì ti ń sáré sí iwájú ni àwọn àdá náà yóó ma là á ní àyà lọ. Nípa bẹ́ẹ̀ yóó la ifun ara rẹ̀ sí ìta. Ìmọ̀ràn yìí dára lójú wa, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ a sì pinnu àti tẹ̀lé ìmọ̀ràn náà. A kó àdá jọ a sì lọ̀ wọ́n, wọ́n mú bí abẹ. Nígbà tí ó di òru a lọ ri àwọn àdá náà mọ́lẹ̀ sí ojú ọ̀nà Òjòlà-ìbínú a sì kọ ojú àwọn àdá náà sí òkè lọ. Lẹ́hìn èyí, a di ẹrù wa silẹ̀ olúkúlùkù sì mú ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́ ṣùgbọ́n púpọ̀ nínú àwọn oògùn wa ń bẹ lọ́wọ́ Ewédayépọ̀. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ní kùtùkùtù, Òjòlá-ìbínú múra lóòótọ́ ó ń lọ wẹ̀ láìmọ̀ pé ọjọ́ ti pé tí Olódùmarè ó sọ fún pé òun ń bẹ. Nígbà tí ó gbé ẹnu lé ojú àdá mímú àdá bẹ̀rẹ̀ sí gé e òun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sálọ́ sí iwájú, àdá ń la inú rẹ̀ lọ. Nígbà tí ó ṣe ni Òjòlà-ìbínú kígbe ńlá tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ará ìlú náà jí lójú oorun tí ilẹ̀ sì mì tìtì. Ẹ̀dá ńlá yìí sì bẹ̀rẹ̀ sí jà ṣùgbọ́n ibi tí ó ti ń ṣe èyí ni gbogbo ìfun rẹ̀ ti jáde tí gbogbo ilẹ̀ kún fún ẹ̀jẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ sì ṣẹ̀ láàárin àwọn èjó wọn-ọnnì. Kí Òjòlà-ìbínú tóó kú, ó mọ̀ pé àwa ni, ó sì kígbe wa lọ sí ọ̀run. Ó ké lóhùn rara wí pé: ‘Ènìyàn! – Ènìyàn! – Ènìyàn! – mo lọ fún yín o!’ Bẹ́ẹ̀ ni ó sì wáá jẹ́ pé, ní ìgbà náà tí Òjòlà-ìbínú sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run Ọba, ìfun jáde, ẹ̀dọ̀ jáde, àpòkókú yọ sí ìta gbangba. Kí Olódùmarè má ṣe jẹ́ kí irú eléyìí dé sàkání wa. Ṣùgbọ́n àwa náà ti mọ̀ pé ẹni tí ó à olórí ejò fa ìjàngbọ̀n lẹ́sẹ̀, ẹni tí ó bá ti hu irú ìwà tí àwa hù nì, ojú olúwaarẹ̀ yóò rí nǹkan. Nígbà tí abàmi ẹ̀dá náà ti kígbe ni gbogbo wa ti fún ṣòkòtò le; ṣùgbọ́n nígbà tí olúkúlùkù wa ti mú àdá tí a gbé ìbọn tán a rí i pé oògùn ọwọ́ wa kò ní í lè tó fún ìjà náà nígbà tí a si ń fẹ́ẹ́ lo àwọn oògùn pàtàkì tí a mú fún Ewédayépọ̀ pamọ́ a kò rí Ewédayépọ̀ mọ́, ó ti sálọ bámúbámú. Àṣée, igbà tí Òjòlà-ìbínú ké igbe ńlá, Ewédayépọ̀ gun òkè àjà lọ! Ibi tí a ti ń wá Ewédayépọ̀ kiri ni ẹni kan ti wáá yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sọ fún wa wí pé Ewédayépọ̀ kò sí nínú ìyàrá àti wí pé ó ti sá gun òkè àjà lọ. Eléyìí mú kí n lọ wo òkè àjà wò bòyà òótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, nígbà tí mo sì máa dé ọ̀hún ńkọ́, mo bá ọkùnrin náà níbi tí ó lé góńgó sí, mo bá gba àwọn oòg[pun, mo ku àpò oògùn wa mọ́ ọn ní àtàrí, mo bá ń lọ tí mo ń pòṣé lọ ní tèmi, òun náà bá fi ìtìjú tẹ̀lé mi. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn wà nínú ayé wa yìí tí wọ́n ń fi ẹnu pe ara wọn ní babaláwo ṣùgbọ́n tí wọn kò ní àyà àti sa oògùn tí wọ́n mọ̀, wọ́n á fi ìbẹ̀rù sọ ara wọn di ènìyàn yẹpẹrẹ. ẹni tí ó ńi oògùn ti kò ní àyà kò lágbára tó ẹni tí ó ní àyà tíkò ní oògùn rárá. Ṣùgbọ́ọ́n a fi Ewédayépọ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ sí ìdí ọ̀ràn yìí, ọ̀rọ̀ náà kò kúrò lẹ́nu wa títí a fi kúrò ní ìklú àwọn ejò tí a sì fi padà dé ìlú wa: nígbà tí Olóhùn-ún-dùùrù bá díde a kọjú sí wa, a ní, Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ìgbà tí Òjòlá-ìbínú ké igbe ńlá, Ewédayépọ̀ ṣe kí ni o? Gbogbo wa sì máa dáhùn pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà wí pé, Ewédayépọ̀ gun òkè àjà lọ.’inú a sì máa bí Ewédayépọ̀, a wí pé: N kò mà fẹ́ o, Olówó-ayé, n kò mà fẹ́ o. Ìgbà míràn a dáhùn a ní, Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́, pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ mà di ọwọ́ rẹ o. Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń sọ sí wa nígbà tí inú wa bá dùn tí a bá ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́. Lẹ́hìn ìgbà tí a gba gbogbo oògùn wa tán a múra ogun-jíjà,àwọn ejò náà sí bá wá fi ìjà pa ẹẹ́ta. Ìjàǹbáforítì ló kọ́kọ́ ddí mọ́ra tán nínú wa bí ó sì ti múra ni ó bọ́ sí òde tí ó kígbe ńlá, ó ní, Ẹni tí ó bá tóó jáde kí ó jáde, Ìjànbáforítì ṣetán, Ìjànbáforítì ń lọ.’ Kí ní ó wí bẹ́ẹ̀ ṣe? – ogunlọ́gọ̀ àwọn ejò tí wọ́n tí dúró yí ààfin po wáa mọ̀ pé àwa ló pa ọba wọn kí á sì tóó ṣẹ́ ojú pẹ́ẹ́, Ìjànbáforítì ti jáde, ó tọ̀ wọ̀n lọ, díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn wa náà sì tẹ̀lé e lọ. Èmi àti Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ àti Olóhùn-un-dùuùrù wwà nínú ààfin lóhùn-ún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó kù a ń múra lọ́wọ́. Ìgbà tí ọba ti kú ni gbogbo àwọn ìránńṣẹ́, ìjòyè, ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ tí ó ń gbé ní àa[fin ti sá jáde. Nígbà tí àwa múra tán ní ààfin tí máa jáde ti àwa ti ibọn àti àdá wa, a bá àwọn ènìyàn wa nínú ìjà ńlá. Àwọn ejò lọ́ mọ́ Ìjànbáforítì lára tó bẹ́ẹ̀ tí a kò fi rí ara rẹ̀ lóde mọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí a wo ilẹ̀ ṣe ni a rí òkú ejò ní ilẹ̀ lọ bẹẹrẹ ṣùgbọ́n bí wọ́n ti kú lọ tóó nì, àwọn tí ó kú kò já mọ́ nǹkan kan lára àwọn tí kò kú. Gbogbo wa ló ti mú aporó tí Baba-Onírùngbọ̀n yẹukẹ ti fi fún wa. Nítorí náà oró ejò kò tu irun kan lárá wa ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn tí ó jáde ní ààfin ló mu oògùn yìí nítorí nígbà tí á ń mu ún a kò rí àwọn mẹ́fà kan báyìí, ígbà tí ìjà náà sì gbóná, márùn-ún kú nínú wọn. Èyí ẹ̀kẹfà tí í ṣe àbúrò Àgùntàn-ìnàkí ní ìdí ìyá, orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Ilé-ni-ikú-wà, kú lójú ọ̀nà nígbà tí a kúrò ní ìlú náà tán. Ìjà yìí pọ̀ rékọjá ohun tí ẹnu lè sọ ṣùgbọ̀n ní ìgbẹ̀hìn a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Ọba wí pé àwa ní ó borí. Nígbà tí ó ṣe tí ó bẹ̀rẹ̀ sí rẹ̀ wá, Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ tí kò ti jẹ epo tí kò jẹ iyọ̀ ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ọ̀ yanrìn ó bù ú sí inú ìkòkò ńlá lọ, lẹ́hìn èyìínnì ó mú omi tí ó wà nínú ìgò tí Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ fi fún wa, ó wọ́n omi náà sí àwọn yanrìn náà lára ó sì kígbe lóhùn rara, ó wí pé: Mo pa á láṣẹ lórúkọ Olódùmarè, Ọlọ́run, Alààyè, Ẹni Mímọ́, Ọ̀gá Ògo, Alátùnúnṣe, Aláfẹ̀hìntì, Aláàánú, Ẹni Ìyanu, Ẹlẹ́dáà Ènìyàn, Ẹlẹ́dàá Ayé, Ẹlẹ́dàá Ọ̀run, Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo tí à ń rí, Ẹlẹ́dàá èyí tí a kò rí, Ẹni tí Òjòlá-ìbínú ń ṣáátá, tí àwọn ẹ̀dá ìyókù ń bu ọlá fún, wí pé, lónìí, tí mo wà nínú ìyọnu, kí àwọn yanrìn wọ̀nyí yípadà kí wọ́n di èèrè olóró kí wọ́n máa bu ejò wọ̀nyí jẹ.’ Nígbà tí ó wí báyìí tán àwọn yanrin wọn-ọnnì yìpadà lóòótọ́ wọ́n di èèrà wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí gé àwọn ejò wọn-ọnnì jẹ. Bí àwọn èèrà tí ń gé àwọn ejò jẹ bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ejò ń fẹ́ẹ́ gé wọn jẹ, ibi ti wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ara àwọn pàápàá ni wọ́n ń bù jẹ, nípa bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù àwọn ejò wọn-ọnnì bẹ̀rẹ̀ sì pa ara weọn, oró àwọn tìkara wọ́n ń mú ara wọn. Nípa ṣíṣe báyìí wọn pa ara wọn tán, b��́ẹ̀ ni a sì ṣe tí a sẹgun wọn. Ìgbà tí a ṣe eléyìínì tán a padà wọ ààfin lọ a kó oúnjẹ jáde a bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. Ṣùgbọ́n kí á tóó ṣe èyí, èmi àti Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ lọ wo Òjòlá-ìbínú níbi tí ó kú sí, nígbà tí a sì wo inú ìfun rẹ̀ a bá àdó méjì, ọ̀kan jẹ́ ti wúrà ọ̀kan sì jẹ́ ti fàdákà. Ìgbà tí mo da orí tèmi tí ó jẹ́ ti wúrà kọ ilẹ̀, owó góòlù bẹ̀rẹ̀ sí jáde, ṣùgbọ́n Ènìyàn-ṣe-pẹ̀lẹ́ mú ti fàdákà, ìgbà tí òun náà sì mú tirẹ̀ tí ó jẹ fàdákà tí ó da orí rẹ̀ kọ ìsàlẹ̀ owó ṣílè bẹ̀rẹ̀ sí jáde. Owó wọ̀nyí ń jáde láéláé ni kò sì tán; òun náà ni mo bá sì fi di olówo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pá níkẹhìn olè jí àdó náà lọ. Gbogbo wa jẹun púpọ̀ ní ààfin Òjòlá-ìbínú a sí mu ọtí pẹ̀lú. Ìjàǹbáforítì mu ọtí yó pátápátá. Nígbà tíó di ojú alẹ́, gbogbo wa di ẹrù wa a gbé e lé orí àwọn tí ó kéré díẹ̀ nínú wa, nítorí a ti pọ̀ díẹ̀ ju bí a ti ṣe kúrò ní ilé Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ lọ. Àwọn tí a bá ní àgbàlá ọba ejò náà tí wọn kò ì ti í kú dàpọ̀ mọ́ wa. Ìjàǹbáforítì dúró sí iwájú àwa náà sì ń tẹ̀lé lọ. Ijó ni a fi kúrò ní ìlú yìí, Ìjàǹbáforítì ni ó sì ń dá orín náà, orúkọ ara rẹ̀ ni ó sì fi ń kọrin náà. Òun ní kí àwa máa wí pé: ‘Ìjàǹbá’ òun á máa wí pé ‘Forítì’. Bí ó ti ń gbé ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan ni àwa náà ń gbé ẹsẹ̀ pọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo tí a ń tẹ̀lé e tí a sì ń pa àtẹ́wọ́. Gbogbo rẹ̀ wáá di: Forítì, Ìjàǹbá – Forítì. Ìjàǹbá – Forítì. Ìjàǹbá – àtí bẹ́ẹ̀ lọ. Báyìí ni a ṣe tí a kú[ro ní ìlú àwọn ejò wọn-ọnnì níbi tì Òjòlá-ìbínú ti ń ṣe ọba wọn. Kò pẹ́ púpọ̀ tí a kúrò ní ìlú náà tí ilẹ̀ fi ṣú, ọ̀nà ni a sì sùn mọ́jú ọjọ́ náà. Títí ilẹ̀ ọjọ́ kejì fi ṣú a kò dé ìlú kan rárá ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọ̀sán ọjọ́ kẹta a dé ibi tí àwọn obìnrin méje wọn-ọnnì wà tí wọ́n ń sáré kiri títí ọjọ́ ayé wọn. Ní àtètèkọ́ṣe, ní ìbẹ̀rẹ̀ ayé pátápátá, ní àkókò ìgbà tí Èṣù ṣubú ní òde ọ̀run, tí Ọlọ́run sì fi ààlà sì agbedeméjì ọ̀run rere àti ọ̀run búburú, igi kan wà ní etí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ tí ó jẹ́ ààlà ní ààrin ọ̀run rere àti ọ̀run búburú, àwọn ará ọ̀run gbogbo a sì máa pe igi náà ní Tèmi-nìkan. Igi yìí ní oríṣiríṣi èèso, èèso rẹ̀ sì dára lẹ́wà gidigid, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kì í fi ọwọ́ kàn án, nítorí ẹni tí ó bá fi ọwọ́ kàn án yóò rí ọ̀ràn, ẹni tí ó bá ká èèso Tèmi-nìkan yóò bá ìbínú Ọlọ́run pàdé. Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbọ́ràn ọmọbìnrin wọn-ọnnì hu ìwà tí Olódùmarè kò fẹ́, wọ́n kúrò ní ibi tí Ọlọ́run Ọba fi wọn sí ni òde ọ̀run wọ́n lọ ká èèso Tèmi-nìkan, nígbà tí wọ́n sì ká a tán wọ́n wá si inú ayé wọ́n fi í fún àwọn ọmọ ènìyàn jẹ àti ìgbà náà ni àwọn ọmọ ènìyàn sì tí ń hu ìwà àbòsí sí ara wọn tí ẹni kan kò fẹ́ kí ẹnì kejì ní ìlọsíwájú bí i tí òun mọ́ tí wọ́n ń kígbe ara wọn káàkiri inú ayé. Ṣùgbọ́n ẹlẹ́sẹ̀ kò ní í lọ láìjìyà àfi bí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà bá tètè ronù pìwàdà. Nítorí tí àwọn obìnrin méje wọn-ọnnì jẹ́ olóríkunkun, Ọlọ́run Ọba fi wọ́n bú ó sì wí ní ìbínú rẹ̀ pé: ‘Ẹ̀yin aláìgbọ́ràn ẹ̀dá, mo dá yín tán ẹ gbàgbé Mi, ẹ lọ fún àwọn ènìyàn Mi ní èèso Tèmi-nìkan jẹ, ẹ si sọ ayé wọn di ewúro! Ẹ máa lọ, ẹ kò gbọdọ̀ padà sí ọ̀run mọ́, ẹ lọ sí inú igbó lọ́hùn-ún nì, ẹ máa sáré kiri títí ọjọ́ ayé yín, kí ẹ jẹ́ ẹ̀kọ́ fún àwọn aláìgbọ́ran, àti òye fún àwọn elétí dídi, ẹ̀yin kì yóó sì kúrò nínú ipò ìbànújẹ́ tí ẹ̀yin wà yìí, títí yóó fi di ọjọ́ àyípadà ohun gbogbo.’ Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run Ọba ti fi àwọnobìnrin méje wọn-ọnnì gégùn-ún nítorí pé wọn kò náání Ẹni tí ó dá wọn. Kí a tóó kúrò lọ́dọ̀ Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ ó ti sọ̀rọ̀ púpọ̀ fún wa nípa wọn ó sì ti pa á láṣẹ fún wa wí pé bí a bá ti ń sún mọ́ etí ọ̀dọ̀ wọn kí a fi aṣọ di etí wa, àti pé ìgbà tí a bá dé ọ̀dọ̀ wọn kí a má ṣe wo apá ibi tí wọ́n wà, àwọn ń bẹ ní apá òsì níbi tí wọn gbé ń sáré kiri tí wọ́n sì ń kọrin burúkú irú èyí tí ó jẹ́ pé tí etí bá gbọ́ ojú yóò fẹ́ẹ́ wo apá ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá rí wọn kò ní í lè llọ mọ́. Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ si ti ṣe àpèjúwe fún wa wí pé nígbà tí a bá ti dé aginjù tí ó dúdú mirinmirin, tí ẹyẹ kan ṣoṣo kò ké, tí aláǹgbá kò sáré, tí ọ̀kẹ́rẹ́ kò gun igi, tí a kò sì rí ojú ẹsẹ̀ ẹranko, kí á mọ̀ pé a dé ọ̀dọ̀ àwọn olórí-burúkú obìnrin náà kí á sì fi aṣọ di etí wa títí a ó fi dé ibi kan tí ó tẹ́jú pẹrẹsẹ. Ó wí fún wa pẹ̀lú pé nígbà tí a bá dé ọ̀dọ̀ wọn gan-an, àyà wá yóò já, irun orí wa yóó sì dìde. Ìgbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ rẹ́, ó ní, ‘Bí ẹ bá tí ń rí àmì wọ̀nyyí, ẹ múra ẹ máa sálọ.’ Lóòótọ́ nígbà tí a máa dé ibẹ̀ ni a ti bẹ̀rẹ̀ sí rí àmì wọn-ọnnì. Lẹ́sẹ̀ kan náà gbogbo wa sì ti fi aṣọ di etí wa a ń lọ. Báyìí ni a ṣe títí a fi la àfonífojì náà já, ṣùgbọ́n nígbà tì a là á já tán tí a wo ààrin wa a kò rí ọ̀kan nínú wa mọ́, ọkùnrin náà ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ Ìbànújẹ́-ìsàlẹ̀ tí ó jẹ́ ẹnì kan tí ojú rẹ̀ kì í fa ni mọ́ra lọ́jọ́ kan, a máa di ẹnu ká duduudu. A dúró títí ní iwájú a kò rí Ìbanújẹ́-ìsàlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ̀ bí ó ti rìn ní àfonífojì náà. A fun fèèrè kò dáhùn, a kígbe títí a kò rrí i títí di òní olónìí. Àwọn ẹlòmíràn wí pé ìgbà tí a dé ọ̀dọ̀ àwọn obìnrin wọn-ọnnì ọkùnrin náà wo ibi tí wọ́n wà ó sì yà sí ọ̀dọ̀ wọn; àwọn ẹlòmíràn wí pé ó ti yà kí á tóó dé ibẹ̀ àti wí pé ó ṣìnà sí inú igbó ni. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ń ṣo tirẹ̀ ṣáá ni a kò sì mọ èyí tí à bá gbàgbọ́, èyí tí ó dá wa lójú ni wí pé àwa àti Ìbànújẹ́-ìsàlẹ̀ ni a jọ kúrò ní ìlú Òjòlá-ìbínú, àwa àti Ìbànújẹ̀-ìsàlẹ̀ kò sì jọ la àfoní-fojì àwọn olórí-burúkú obìnrin já. Nígbà tí a kúrò nínú àfonífojì yìí, a pàdé ẹbọra kan tí ó ń ti ọ̀dọ̀ Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ bọ̀, ojú kan ṣoṣo ni ẹbọra náà ní, a sì jọ kí ara wa dáadáa nígbà tí a pàdé ara wa: nítorí ní àkókò wọn-ọnnì, ẹ̀rù àwọn ẹbọra kò bà wá jú bẹ́ẹ̀ lọ mọ́, ṣe ni a jọ ń pàdé, tí a jọ ń pínyà, tí a jọ ń sọ̀rọ̀, tí a jọ ń ṣe àwàdà, tí a sì jọ ń ṣe àṣàrò fún ara wa, díẹ̀ ló kù kí àwa pàápàá di ẹbọra. Ẹbọra olójú kan yìí ni ó fún mi ní ìwé tí Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ kọsí mi, ohun tí ó sì wà nínú ìwé náà ni èyí: ‘Ilé Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ Ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta, Ní ìtọ́jú ẹbọra olójú kan, àgbègbè ilé Ikú, Agbedeméjì ayé òun ọ̀run, Ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà, Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógójì, Lẹ́hìn ikú Olúwa wa. ‘’’Sí, Ọ̀gbẹ́ni Olóiwó-ayé, Ọmọ Akọ̀wédìran, Olówó-ayé ni ọ̀wọ́n, Láti ìgbà tí o ti kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, n kò yéé ṣe ìdárò rẹ̀, mo sì tànmọ́ọ̀ pé lákòókò tí ìwé yìí yóò bá fi tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ ìwọ yóó tí kúrò ní ìlú àwọn ejò ìwọ yóó sì ti rékọjá àwọn olórí-burúkú obìnrin. Láìṣe-àní-àní, ọ̀spọ̀lọpọ̀ ìyọnu ni ìwọ o ti bá pàdé ṣùgbọ́n mo rò pé o kò ní í gbàgbé gbogbo ìmọ̀ràn tí mo tí máa ń fún ọ nígbà tí ìwọ wà lọ́dọ̀ mi wí pé, kí o tóó lè borí ayé àwọn nǹkan méje pàtàkì ni o níláti ṣe. Èkínní, o níláti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Ọba, kí o fi Olódùmarè ṣe oògùn àjísà rẹ, èkejì, o níláti máa fi òótọ-inú bá àwọn ènìyàn lò, a kò gbọdọ bá ọ ní ìdí kèéta, kí o sọ nǹkan mìíràn fún onítọ̀hún kí o máa gbé igbá rìkíṣí kiri; ẹ̀kẹta, o níláti rẹ ara rẹ sílẹ̀, ẹ̀sẹ̀ ìgbéraga ni ó bí Olódùmarè nínú jùlọ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ọmọ ènìyàn ń dá lórí ilẹ̀ ay’w: nígbà tí ọmọ Olódùmarè wá sí òde ayé ní ijọ́sí, ó wá pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀: wọ́n lóyún rẹ̀ ní ìlú kékeré, wọ́n bí i sí ibi tí ẹran ti ń jẹun, ó bá àwọn onígbèéraga wí ó sí wẹ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ lẹ́sẹ̀; ẹ̀kẹrin, múra sí iṣẹ́ gidigidi, má ṣe fi í jáfara, ìlọsíwájú jìnnà sí ọ̀lẹ ènìyàn, ẹni tí ó ń fi gbogbo ọjọ́ sùn sí orí ìbùsùn kò ní i lè dúró láàárin àwọn ènìyàn pàtàkì láéláé: ẹ̀karùn-ún, máa mú sùúrù fún àwọn ọmọ aráyé, nítorí bí ìwọ kò bá ṣe èyìínì ìwọ yóó di òmùgọ̀ bíi wọn; ẹ̀kẹfà, má ṣe nírètí títí ọjọ́ ayé rẹ wí pé bí o bá ti ń ṣe oore fún àwọn ọmọ aráyé tó ni ìmọ yóó máa rí ọpẹ́ gbà lọ́wọ́ wọn. Díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ènìyàn ni ó moore, aláìmoore ni púpọ̀ nínú wọn, ẹni tí ń ṣe oore mú inú Olódùmarè dùn, ìdí rẹ̀ sì ni èyí tí àwọn ẹlòmíràn kò fi bínú lọ́jọ́ kan kí wọ́n fi oore-ṣíṣe sílẹ̀, àti pàápàá ènìyàn kò lè mọ ẹni tí yóó san oore, ẹni tí ìwọ rò pé yóó moore kò ní í mọ̀ ọ́n, ẹni tí ìwọ kò sì nírètí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí ni yóó mọ oore tí ìwọ bá ṣe fún un tí yóó sì máa ròhìn rẹ káà kiri. Èkeje, má ṣe mọ ti ara rẹ nìkan, ìwọ nìkan kọ́ lo wà láyé, máa ran ọmọnìkejì rẹ lọ́wọ́. Olówó-ayé mi ọ̀wọ́n, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún ìba àkókò díẹ̀ tí a jọ gbé ps, mo sì tún dúpẹ́ owó tí o ná fún àwọn ara ilé mi nígbà tí ìwọ ń lọ. Mo fi ọ́ sí abẹ́ ààbò Ọlọ́run Ọba, Kí Olódùmarè ṣe alátìlẹ́hìn rẹ, Gbogbo àwọn ara ilé mi kí ọ dáadáa, Èmi ni ọ̀rẹ́ rẹ pàtàkì, Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́,’ Báyìí ni ọ̀rẹ́ mi náà kọ̀wé sí mi, nígbà tí mo rí ìwé rẹ̀ àfi bí ẹni pé òun ni mo rí. ènìyàn ni Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́. Ọ̀rẹ́ tí ènìyàn lè gbẹ́kẹ̀lé ni, kì í ṣe ọ̀rẹ́ tí ojú rẹ̀ dùn bí oyin ṣùgbọ́n tí inú rẹ̀ dà bí oró paramọ́lẹ̀, kì í ṣe ọ̀rẹ́ tí ń dé ilé ẹni tí ó ń kí ni ní ìgbà àádọ́ta lóòjọ́ tí ó sì jẹ alága ní ìdí rìkíṣí ẹni. Èmi náà fèsì ìwè ọ̀rẹ̀ mi. Báyìí ní ìwé mi náà ṣe lọ: “ojú ọ̀nà, Igbó Olódùmarè, Ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹfà, Ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógójì, Lẹ́hìn ikú Olúwa wa. Sí, Ọ̀gbẹ́ni Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́, Ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta, Ní ìtọ́jú ẹbọra olójú kan, àgbègbè ilé Ikú, Agbedeméjì ayé òun ọ̀run. Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ mi ọ̀wọ́n, Ní orí ìrìn ni mo ti rí ìwé rẹ gbà. Àkókò tí àárò rẹ sí ń sọ mi gan-an ni ìwé rẹ yìí tẹ̀ mí lọ́wọ́. Nígbà tí mo ń ka ìwé rẹ̀ náà ṣe ló dà bí ẹni pé mo rí ọ gan-an. Láti ìgbà tí mo ti kúrò lọ́hùn-ún kò sí ọjọ́ kan tí n kò rántí rrẹ, àárò rẹ sọ mi púpọ̀, ìgbà púpọ̀ ni mo sì ń lá àlá rí ọ. Kí n tóó máa bá ọ̀rọ̀ mi lọ mo níláti kọ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún aájò mi tí o ṣe nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ. Nítorí, àfi Ọlọ́run Ọba ló lè san oore tí o ṣe fún mi. Kí ni mo ṣàì fi ẹnu mi jẹ tán ní ilé rẹ? – Iyàn ni tàbí ọkà tàbí iṣu tàbí àgbàdo? Ajá kì í gbàgbé olóore rẹ̀: n kò jẹ́ gbàgbé rẹ láéláé, ènìyàn ni ọ́. Háà! Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ o ṣe e o, bí ìmàle ti ń rántí Ànábì tí onígbàgbọ́ ń rántí Ọlọ́run Ọba bẹ́ẹ̀ náà ni n ó máa rántí rẹ láéláé. Mo sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún ìmọ̀ràn gbogbo tí o fún mi, n kò gbàgbè wọn rárá, wọ́n ń bẹ ní àtẹ́lẹwọ́ òsì mì n kò sì ní í fi ọwọ́ náà jẹun. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ìmọ̀ràn ní iye lórí púpọ̀, òmíràn dà bí fàdákà, òmíràn dà bí wúrà, òmíràn sì dà bí dáyámọ́ndì tíí ṣe òkúta olówó iyebíye. Ìbá ṣe pé ènìyàn ń san owó fún ìmọ̀ràn ni, òmíràn ìbá ju ẹgbẹ̀rùn pọ̀nùn lọ. Nítorí náà ẹni tí ó fún ni ní ìmọ̀ràn dáadáa nǹkan pàtàkì ni olúwaarẹ̀ ṣe. Kí Ọlọ́run má ṣe fi ni lé ọ̀tá lọ́wọ́, ìmọ̀ràn ọ̀tá dà bí ọbẹ̀ ìtàdógún ṣùgbọ́n ìmọ̀ràn ọ̀rẹ́ dùn ju oyin ìgàn lọ, ìdí rẹ̀ sì nìyí tí ó fi yẹ kí ọmọlúwàbí máa ronú kí ó tóó gba ìmọ̀ràn tàbí kí ó tóó tàpá sí i, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ mi ni ìwọ í ṣe, ìwọ Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́, ìmọ̀ràn rẹ sì ti wọ̀ mí ní ibi kọ́lọ́fín agbárí lọ. Èmi pàápàá ní ìmọ̀ràn tí mo níláti fún ọ nítorí nǹkan tíó bá kàn ọ́ kan mí. Mo ti ṣe àkíyèsí nígbà tí mo wà lọ́hùn-ún pé inú rẹ funfun ó ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí o mọ̀ pé kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni inú gbogbo aráyé rí. O níláti kíyè sára gidigidi, nítorí ẹ̀rù àwọn aládùúgbò rẹ ń bà mí. Ẹni tí ‘;o mú ilé ti Ikú mú ilé ti nǹkan, ẹni tí ó mú ilé ti Àrùn mú ilé ti ìjàngbọ̀n, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń gbọ́ igbe àkùkọ ọ̀run níláti ṣọ́ra gidigidi. Ẹ̀hìnkùnlé ni ọ̀tá wà, ilé ni aṣeni ń gbé, bí ikú ilé kò pa ni ti òde kò lè pa ni, ọmọ-ọ̀dọ̀ ní ń mọ àṣírí olúwa rẹ̀, obìnrin ẹni ní ń mọ àtisùn ẹni. Nítorí náà kí Olódùmarè gbà ọ́ lọ́wọ́ ọ̀tá ilé àti ọ̀tá òde. Ọ̀rọ̀ púpọ̀ irọ́ ní ń mú wa, nítorí náà ọ̀rọ̀ mi kò nì í gùn gbọọrọ. Bá mi kí àwọn ará ilé rẹ, Àlàáfíà ni àwa náà wà níhìn-ín, Kí Ọlọ́run má kọp àtúnrí, Bí ẹlẹ́mìí kó bá gbà á, Ọjọ́ ń bọ̀ tí a óò tún fi ojú gán-ánní ara wa, Èmi ni ọ̀rẹ́ rẹ lójú méjèèjì, Olówó-ayé, Ọmọ Akọ̀wédìran.’ Bẹ́ẹ̀ ni mo kọ̀wé mo sì fi ìwé náà fún ẹbọra olójú kan kí ó bá mi fún ọ̀rẹ́ mi. N kò ní í lè sọ gbogbo nǹkan tí ojú mi rí kí ó tóó di pé mo dé ibib tí mo ti kọ́ ṣìnà sí inú Igbó Olódùmarè nígbà tí mo kọ́ kúrò ní ìlú mi. Èyínì ni ibib tí Ọba Igbó Olódùmarè wà tí mo fi ìyàwó mi sí nígbà tí mo múra àti lọ ṣe ọdẹ tí ó fi di pé mo bá ara mi tí mo lé ténté lórí igi fún ìgbà pípẹ́. Bí mo bá ní kí n tún máa sọ ohun tí ojú mi rí nígbà tí mo ń padà bọ yìí èyínì yóó gbà ìwé mìíràn gidigbi. Ṣùgbọ́n ohun tí mo lè sọ ni pé oṣù kẹfà tí mo ti rí ìwé ọ̀rẹ́ mi yìí gbà, ìwé Baba-onírùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́, ni mo tóó dé ibib tí Ọba Igbó Olódùmarè fi ṣe ibùgbé. Ogunlọ́gọ̀ ìlú kéékèèkéé ni a kàn lójú ọ̀nà, àǹfààní tí mo sì rí nínú ìlú wọn-ọnnì pọ̀ gidigidi. Mo ní owó kún owó mo sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oògùn tó bẹ́ẹ̀ tí mo níláti wá aláàárù kí wọ́n bá mi máa gbé ẹrù mi ni. Ṣùgbọ́n ní ìkẹhìn ṣáá mo dé ibi tí Ọba Igbó Olódùmarè wà. Bẹ́ẹ̀ ni lọ́jọ́ tí Ọba Igbó Olódùmarè àti èmi fi ojú rí ara wa, ayọ̀ pàdé ayọ̀, ẹ̀rín ń gbé ẹ̀rín ní ìyàwó, ijó ń bá ijó ṣiré, oúnjẹ ń pádè oúnjẹ, ènìyàn àti ẹbọra ń fi ọwọ́ kọ́ ara wọn lọ́rùn, òkìkí gba inú Igbó Olódùmarè kankan. Nígbà tí èmi àti ẹbọra náà kí ara wa tán tí mo sì béèrè ìyàwói mi, ó wí fún mi pé ẹ̀gbọ́n mi ti wá sí ibẹ̀ àti pé ó ti mú ìyàwó náà lọ sí ìlú wa nítorí pé wọn kò gbúròó mi. Òun náà sì tún wí fún mi pé ìyàwó mi ti bímọ àti pé orúkọ tí wọn sọ ọmọ náà ni Àkàrà-oògùn. A gbé ọjọ́ mẹ́ta ní ààfin ọba yìí, nígbà tí mo wí fún un pé mo fẹ́ẹ́ lọ sí ilé kí n baà tètè lọ rí ìyàwó mi àti ọmọ rẹ̀ tuntun, òun náà sì gbà bẹ́ẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n bi kò bá sí ti ìyàwó mi ni kì bá tí jẹ́ kí n lọ nítorí ó ti wí fún mi ní ijọ́sí pé kí n máa gbé ọ̀dọ̀ òun. Ọba náà ṣe ènìyàn púpọ̀ nǹkan kan kò si jẹ ní ìyà lọ́dọ̀ rẹ̀ rárá, ó ṣe ìtọ́jú mi dé góńgó, kò sí nínú àwọn ẹlòmíràn tí ó jẹ́ pé nígbà tí Ọlọ́run bá ti jàjà gbé wọn dé ipò ńlá tán wọ́n á máa fi ojú kékeré wo àwọn ẹlòmíràn, wọn a máa rò pé àwọn nìkan ni ayé wà fún láìmọ̀ pé ọmọ kékeré a máa mọ ibi ìṣubú àgbàlagbà, ẹni tí ó tẹ ọká ní ìrù mọ́lẹ̀ yóò rí ìjà ejò, ẹni tí ó dúró ní bi gẹgẹrẹ mọ́tò ń fi ikú ṣiré, ẹni tí ó dàgbà tí kò ní ìwà àgbà nínú, ọmọ kékeré ni. Bẹ́ẹ̀ ni mo kúrò ní ọ̀dọ̀ ọba náà mo sì wá sí ìlú mi. Inú mi dùn nígbà tí mo rí àwọn ènìyàn mi. Ìyàwó mi yọ̀ púpọ̀, a ṣiré títí ilẹ̀ fi ṣú, a sì jẹun tí ó gbádùn nítorí mo mú ẹyẹ àparò bọ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún mi nígbà tí mo fi í sí ibùdó ní Igbó Olódùmarè tí mo ń lọ ṣe ọdẹ. Ọmọ mi ti bẹ̀rẹ̀ sí rìn dáadáa kí n tóó kí n tóó dé, àkọ́bí mi, àkàrà-oògùn, n kò si lè sọ bí ayọ̀ mi ti pọ̀ tó nígbà tí mo rí i. ‘Báyìí ni ìtàn ìgbésí-ayé mi lọ, èyí tí mo sì kọ sílẹ̀ yìí yóó fi han àwọn ọmmọ mi lẹ́hìn ọ̀la irú ohun tí ojú mi rí kí ó tóó di pé mo fẹ́ ìyàwó mi àti èyí tí ojú mi rí lẹ́yìn tí mo fẹ́ ẹ tán kí n tóó di ẹni tí ó lè fi ojú rí ọmọ tí ó jẹ́ àkọ́bí mi.’ Báyìí ni bàbá ọ̀rẹ́ mi kọ apa’kan nínú ìtàn ìgbésí-ayyé rẹ̀ sílẹ̀, Ọjọ́ méjì ni mo sì gbà kí n tóó kọ apá kan yìí náà tán, mo kọ̀wé títí gbogbo èjìká ń ro mi gooro, Àkàrà-oògùn tí ó jẹ́ ọmọ Olówó-ayé ni ẹni tí ń ka ìtàn náà fún mi. Nígbà tí ó si kà á tán ó dáhùn, ó ní: Ọ̀rẹ́ mi, iṣẹ́ tí Olódùmarè bá rán ọ, jẹ́ ẹ fún àwọn ọmọ aráyé; má ṣe jẹ́ kí ó rẹ̀ ọ́. Bí àwọn ènìyàn bá ka ìwé rẹ tí Ọlọ́run Ọba sì ti ibẹ̀ kọ́ wọ́n lọ́gbọ́n èyínì ni pé wíwá sí ayé rẹ ṣe ọmọnìkejì rẹ ní rere. Jọ̀wọ́ mo bẹ̀ ọ́, ìrẹ̀lẹ̀ ṣe pàtàk�� nínú ìwà, má ṣe fi ara rẹ wé àwọn ẹlòmíràn, ìgbà tí wọ́n bá lo ẹ̀bún tí Olódùmarè fún wọn tán, wọn a gbé ìgbéraga wọ̀ bí ẹ̀wù wọn a wí pé àwọn nìkan ṣoṣo ní ń bẹ. Kò sí ẹni tí ń bẹ àfi Ọlọ́run Ọba. Rántí pé ẹni tí ó dá erùpẹ̀ ilẹ̀, tí ó dá omi, tí ó dá igi, eeléyìínì lè lo àwọn ẹlòmíràn fún ìràpadà àwọn aráyé. Dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo bí a bá kà ọ́ yẹ láti ran ẹlòmíràn lọ́wọ́, ìwọ ọ̀rẹ́ mi. Mo dúpẹ́ púpọ̀ fún iṣẹ́ tí ó ṣe fún mi láti ọjọ́ tí mo ti ń tọ̀ ọ́ wá wọ̀nyí mo sì ṣe àkíyèsí pé iṣẹ náà kò jọ̀ lójú ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ ó ń fún ọ ní ìrẹ̀lẹ̀ ni. Olódùmarè mọ ohun tí òun ń ṣe: kò jẹ́ sọ wúrà Rẹ̀ sí iwájú ajá, bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ gbé òkúta olówó iyebíye rẹ̀ síwájú ẹlẹ́dẹ̀, ẹni tí ó bá mọ àǹfààní lò ni Ọlọ́run Ọba ń fi àǹfààní fún. Kí Olódùmarè fún ọ ní ẹ̀mí gígùn; kí Ọlọ́run fún ọ ní ìbàlẹ̀ ọkàn; kí Ẹlẹ́dàá rẹ má ṣáì fi àlááfíà jíǹkí rẹ. Ó tó àkókò ná wáyí tí mo níláti padà sí ibib tí mo ti ń wá, bí Ọlọ́run bá sì dá ẹ̀mí sí, ọjọ́ ń bọ̀ tí a óò tún fi ojú rí ara wa. Bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin náà sọ, nígbà tí ó si dákẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ n kò rí i mọ́. Ọ̀rọ̀ náà ni èyí, ẹ̀yin ènìyàn wa. Mo rò pé láti ìgbà tí ẹ tí n ka ìwé yìí, ẹ kò ní ṣàì máa fa ọgbọ́n jáde fún ara yín. Àwọn àgbà tí wí pé ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n kì í jẹ́ kí a pa àgbà ní wèrè. Ẹni tí ó wà nínú ayé tí kò ní òye ó dábì ẹranko tí ó ṣègbé. Ìyá mi a máa sọ̀rọ̀ kan fún àwa ọmọ rẹ̀ nígbà tí a wà ní èwe ó sì sọ ọ fún wa títí a fi dàgbà, a máa wí báyìí pé ẹni tí ó bí ọmọ tí ọmọ náà kò gbọ́n ń ṣe òwò àṣedànù. Ẹ má ṣe gbàgbé wí pé bí ayé tí dùn tó bẹ́ẹ̀ náà ni ìṣsòro inú rẹ̀ pọ̀ tó. Ìgbà tí ènìyàn bá rí ìṣòro kan ṣoṣo nígbà míràn a dà bí ẹni pé kí olúwaarẹ̀ kú lẹ́sẹ̀ kan náà. Bí ẹ bá ti ń bá ìṣòro pàde nínú ayé mo fẹ́ kí ẹ máa bú sí ẹ̀rín kí ẹ sì mọ̀ pé ọjọ́ ń bọ̀ tí ìgbádùn yóó wọlé tọ̀ yín wá. Ọmọ ilé-ìwé tí kò ṣe dáadáa nínú ìdánwò lónìí, bí ó bá múra ọjọ́ ń bọ̀ tí yóò tún ṣe dáadáa tí ayọ̀ yóó bo ìbànújẹ́ mọ́lẹ̀ batakun. Mo fẹ́ kí gbogbo ènìyàn fi í sí ọkàn pé kò dí ẹni tí kò ní Igbó Olódùmarè tirẹ̀ láti lọ nínú ayé, Igbó Olódùmarè ti ẹni kan yàtọ̀ sí ti ẹni kejì, kí Olódùmarè jẹ́ kí olúkúlùkù ti Igbó Olódùmarè tirẹ̀ dé láìní ìpalára. Ìṣòro tí a kò lágbára láti gbé kí Ọlọ́run Ọba má ṣe gbé e kà wá láyà. Ẹ má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ tí ẹ gba nípa ìwà ìrẹ̀lẹ̀. Ìgbéraga ń gbílẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lójoojúmọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìgbéraga ni gbòǹgbò ìparun. Ipòkípò tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ ayé mo fẹ́ kí ẹ gbé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀ bí ẹ̀wù. Ọba tí ó tóbi kò tó ìránńṣẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Ọba. Ẹ má sì ṣe gbàgbé àti máa fi òótọ́-inú bá àwọn ènìyàn lò: èyìínì ni pé kí ẹ má ṣe wá ibi fún ọmọnìkejì yín, kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ki bẹ́ẹ̀ kọ́ yín sí jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́. Ṣùgbọ́n òdodo kì í ṣe nnǹkan yẹpẹrẹ nítorí bí ẹ kò bá múra dáadáa àti ṣe òdodo á jẹ́ ìṣòro: nítorí bí ẹ bá ti ń yọ ẹlòmíràn kúrò nínú kòtò,ẹni tí ẹ ń yọ ‘tun lè máa gbìyànjú àti tí yín sí inú ọ̀gbun. Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ń bá òótọ́-inú yín lọ, inú ọ̀gbun tí òun ń ffẹ́ẹ́ tì yín sí ni yóò bá ara rẹ̀ tí yóò kún inú kòtò bámúbámú. Bí ẹ bá ń lo òótọ́-inú, Olódùmarè yóò dúró tì yín bí òkè ńlá, ẹni tí ó bá sì kọlù yín yóò rí ìpalára. Ẹ tọ́jú iṣẹ́ yín dáadáa, ohun tí ó ṣe pàtàkì ni ibi tí a bá ti ń rí òkèlè ẹni. Ó lòdì sí ìlànà Olódùmarè ó sì ìríra lójú àwọn ọmọ aráyé wí pé kí ọmọ tí a bí nínú ẹni máa hùwà àìbíkítà sí ni. Nítorí náà kò sí ìwà tí àwọn ọmọ ilé-ìwé lè hù tí ó tayọ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ níwájú àgbàlagbà, ọ̀wọ̀ fún àwọn òbí, àti itẹríba fún ìlànà Ọlọ́run Ọba. Mó fẹ́ kí ọmọ tí ó bá rí i pé òun ń hu ìwà tí ó ń bí àwọn òbí nínú,m tí ó ń ba àwọn olúkọ́ lẹ́rù, tí ó sì ń fún iyèkan ní ìbànújẹ́ ṣe ìpinnu àti fi ìwà bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ ní ọjọ́ tí ó bá rí ìwé yìí, nítor�� ẹ̀hìn ọ̀la. Mo ṣe bi ọ̀kan nínú àwọn olóye lórí ayé àtijọ́ tí wí fún wa nínú ìwé ní ijọ́sí wí pé, ọmọ tí ó bá hùwà àìbìkítà sí òbí rẹ̀, ẹyẹ àkàlàmàgbò ni yóó yọ ojú ọmọ náà jẹ! – Kí Olódùmarè má ṣe jẹ́ kí ẹyẹ àkàlàmàgbò yọ ojú àwọn ọmọ ilé-ìwé wa jẹ. Ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, ayé ń lọ, ojoojúmọ́ ń mú ọjọ́ kan kúrò nínú ìgbésí-ayé olúkúlùkù, bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́-ayé ọmọ ènìyàn kò ju kékeré lọ. Àkókò tí a bá sì ní í inú ayé yìí, mo bẹ̀ yín ẹ má ṣáìjẹ́ kí á lò ó dáadáa: kí á lò ó pẹ̀lú ayọ̀, kí a lò ó pẹ̀lú ẹ̀rín kí á sì fi inú dídùn bo ìbànújẹ́ mọ́lẹ̀ batakun. Báyìí ni ìtàn eléyìí parí. Mo kí gbogbo yín ẹ kú àtijọ́ o. Kí Olódùmarè tọ́jú ilé yín fún yín kí Ó sì tọ́jú ọ̀nà yìn pẹ̀lú. Ẹni tí ó ń wá owó kí Olódúmarè fún un ní owó àǹfààní; ẹni tí ó ń wá ọmọ kí Ẹlẹ́dàá fún un ní ọmọ àlàáfíà; ẹyí tí ó wá iṣẹ́ kí Ọ̀g;a Ògo fún un ní iṣẹ́ tí yóó ṣe é ní rere. Kí Ọba Oníbú ọrẹ bá abiyamọ tọ́jú ọmọ; kí Ó fún wúndíá ní ọkọ àǹfààní; kí Ó fún ọmọkùnrin ní ìyàwó àlàáfíà; ọmọbìnrin tí kò fẹ́ẹ́ ní ọkọ àti ọmọkùnrin tí kò fẹ́ẹ́ní ìyàwó kí Olódùmarè fún wọn ní ìgbésí-ayé rere. Kí Ó fi ìrẹ́pọ̀ sí ààrin orogún; kí Ó fi ilẹ̀ ọlọ́ràá fún àwọn àgbẹ̀, kí Ó fún àwọn tí ń ṣ’iṣẹ́ mìíràn ní iṣẹ́ rere ṣe; kí Ó fún àwọn aláìsan ní ìlera; kí Ó fi ọgbọ́n fún àwọn ọba, kí Ó fi òye fún àwọn ìjòyè, kí Ó fi ìmọ̀ fún àwọn ọmọ ilé-ìwé; kí Ó tọ́jú àwọn olùkọ wọn; kí Ó sì máa tọ́ àwọn alágbára sí ọ̀nà òtítọ́. Ó dígbà díẹ̀ ná, Kí Olódùmarè tún jẹ́ kí á máa gbúròó ara wa o. D. O. Fágúnwá ÌRÌNKÈRINDÒ NÍNÚ ÌGBO ELÉGBÈJE D.O. Fágúnwà Ọ̀rọ̀ Àkọ́sọ Ìwé yìí wà fún gbogbo ènìyàn ní ilẹ́ Yorùbá, ó wà fún ọmọdé, ó wà fún àgbàlagbà, ó sí wà fún ẹnikẹ́ni lóde ayé ṣá tí ó mọ èdè Yorùbá á kà dáadáa. Ní pàtàkì, ìwé yìí wà fún àwọn ọmọ ilé ìwé láti kà gẹ́gẹ́ bí ìwé kíláàsì tí olùkọ́ bá rò pé ó yẹ fún, bẹ́ẹ̀ ni bákan náà ló tún wà fún àwọn ti ń ṣe ìdánwò kémbírìíjì láti fi kọ́ ìjìnlẹ́ Yorùbá. Ẹ ó ríí pé mo fi ìwé náà júbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọn wà láyé lónìí, mo gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn wọ́nyí wọ́n sí ti àṣẹ náà fún mi pé ki n fi júbà àwọn, ṣùgbọ́n ó ní ìdí pàtàkì tí mo fi fi ìwé yìí júbà wọn. Awọn wọ̀nyí wà láàrin àwọn ènìyàn pàtàkì tí mo rò pé ó yẹ kí ọmọ Yorùbá máa rántí látí ìran dé ìran. Ọ̀jọ̀gbọ́n Margaret Read, obìnrin ni, ó sì yẹ kí ọmọ Yorùbá kọ́ ọgbọ́n lára obìnrin yìí, púpọ̀ nínú wa ni o sì ń wí pé kí ni obìnrin lé ṣe, pẹ̀lú ìrọ́jú sí ni àwọn òbí mìíràn fi ń fi ọmọ wọn sí ilé ìwé bí o bá sá ti lè jẹ́ obìnrin. Margaret Read ni ọ̀gá Ilé Ẹ̀kọ́ ńlá tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó bá lọ sí ìlú Gẹ̀ẹ́sì láti kọ bí a ti ṣe ń ṣiṣẹ́ Olùkọ́ tí ń kọ́ ìwé wọn, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn láti orígun mẹ́tẹ́ẹ̀rin ayé lo ń wá, a kò sì lè ka iye àwọn ọkùnrin tí o ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ obìnrin yìí ni bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Ṣùgbọ́n ọmọlúàbí ni, kò jẹ́ fi ojú pa ẹnikẹ́ni rẹ́ kó sì mọ ti ara rẹ̀ nìkan. Àpẹẹrẹ ni èyí fún gbogbo yín, ẹ̀yin ènìyàn wa. Ẹni ọ̀wọ̀ (Hon) R.A Mcl. Davidson tíí ṣe alákòóso ẹ̀kọ́ ní nììjííríà lákòókò yìí jẹ́ ẹnìkaan tí o ti pẹ ní ilẹ̀ wa. Lóòótọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ Alákòóso Ẹ̀kọ́ ló ti wà ni nàìjíríà rí, ṣùgbọ́n púpọ̀ nínú wọn ló jẹ́ pé wọ́n ti ibòmíràn wá ṣe Alákòóso Ẹ̀kọ́ ni nàìjíríà ni láàjẹ́ pé àwọn pàápàá dé nàìjíríà rí. kò rí bẹ́ẹ̀ fún ipò kékeré, o siṣẹ́ títí o fi dé ipò gíga. Ko sí ẹni náà tí ó lé mọ Davidson ní àkókò tí o fì ń ṣe Olùdánwò ti o n yí ilé ìwé kékeré kirir tí yóò rí i pé ó dé ipò ńlá yìí lónìí ti ẹnu lè yà. Oníṣẹ́ ni ọkùnrín náà ìgbéga ẹ̀ sì tó ẹ̀kọ́ fún ìwọ àti èmi. Ìgbésí ayé Bísọ̀bù S.C Phillips ni nǹkan pàtàkì láti kọ́ ọmọ Yorùbá. Ó jẹ́ ẹni tí a nílati máa rántí láti ìran dé iran wa. Ẹyin náà mọ̀ pé àbùkù àwa Yorùbá ni èké ṣíṣe, àti sọ òdodo a máa ṣòro fún ni. Bí o bá wi fún ẹnìkan pé máṣe bá mi lo Yorùbá “ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ ni” “maṣe púrọ́ fún mi”. Ìgbà tí a bá sì wò bí ojú Yorùbá ti là tó kí Gẹ̀ẹ́sì tilẹ̀ tó gòkè, tí ó sì jẹ́ pé kò sí ẹ̀yà kan ní nàìjíríà tí ó lè wí pé òun lajú ju Yorùbá lọ títí di òní olónìí, ẹ ó ríi pé bí a bá lè mú irú àbàwọ́n báyìí kúrò lára wa ìlọsíwájú wa yóò máa ya gbogbo ara ayé lẹ́nu ni. Ṣùgbọ́n Bísọbù Phillips fi hàn ni pé kì í ṣe gbogbo ọmọ Yorùbá ni o ń purọ́. Ta ni ẹni náà ní òde ayé yìí, yálà dúdú, yálà funfun tí ó lé wí pe Bísọ́bù Phillips bá òun lo Yorùbá? Kò sí, àti ẹni tí ó bá máa pe àgùntàn ni màálù, tí o pe mọ́tò ní kẹ̀kẹ́, tí o pe ọmọtúndé ní Akíntúndé, tí ó pe ará ayé ní ará ọ̀run. Ọ̀ótọ́ nìkan ni Bísọ̀bù yìí máa ń sọ, gbogbo ènìyàn sì ti mọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ fún un. Àpẹẹrẹ ni èyí fún gbogbo wa. Bí ẹ̀rù bá ń bà ọ́ láti sọ òótọ́ máṣe gbàgbé Bísọ̀bù Phillips olódodo nítorí Bísọ̀bù yìí tí ó jẹ́ asáájú pàtàkì fún ni kò fi èké kọ́ ìwọ́ àti èmi. Ọba Ọlagbegi II tí ó jẹ́ Ọlọ́wọ̀ ní ọ̀wọ̀ lónìí jẹ́ ẹni àkíyèsí pàtàkì kan. Ìgbésí ayé rẹ̀ fi hàn ni ohun tí ènìyàn lè fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe. Ta ni ẹni náà tí ó lè gbọ́ kí Olọ́wọ̀ sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì tí kò ní rò pé ó ti jáde ní fásitì tàbí pé wọ́n bíi sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni? Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ́ nǹkan rẹ̀ fún ara rẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀wọ̀ lónìí ti yóò bojúwo ẹ̀yìn tí àyípadà rere gbogbo tí ó dé lákòókò Ọlagbegi II kò ní yà lẹnu, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọmọ Yorùbá tí yòó gbọ́ kí Ọlọ́wwọ̀ yìí sọ̀rọ̀ láàrin àwọn ìgbìímọ̀ pàtàkì gbogbo tí ó máa ń lọ tí kò ní fi ọba yìí ṣe fọ́rífọ́rí. Ọba Ọlagbegi II kúrù ní ǹǹkan yẹpẹrẹ, àfi bí a bá máa tan ara ẹni jẹ. Omidan J.A Mars pẹ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ wa, ó dúró gẹ́gẹ́ bí àna fún púpọ̀ nínú ọmọ Yorùbá nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin tí o ti kọ́ ni wọ́n ń pè é ní ìyá tí wọ́n sì ti di ìyàwó ènìyàn pàtàkì káàkiri. Gbogbo agbára ni obìnrin náà fi ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ tí wọ́n bí lójú rẹ̀ tiwọ ilé ọkọ láti ọjọ́ pépẹ́ a kò gbọdọ̀ gbàgbé obìnrin yìí láéláé. Omidan T.V Herklots jẹ́ obìnrin tí o mọ ìwé lọpọlọpọ. Obìnrin yìí kò ba tì ṣiṣẹ lábẹ́ C.M.S bí ó bá ṣe pé owó ló ń wá kiri. Lónìí, òun ni Alága ìpàdé àwọn alákòóso ẹ̀kọ́ tí wọ́n jẹ́ ènìyàn pàtàkì gbogbo ní ilẹ̀ Yorùbá, bẹ́ẹ̀ ni ìgbésí ayé obìnrin náà fi hàn ni pé nǹkan mìíràn wà tí o lágbára jú owó lọ. Kí ènìyàn mu kí ayé ọmọ ẹlòmíràn dára lágbára ju ohun gbogbo . Ó tun fi han ni pé obìnrin lè ṣe nǹkan ńlá; nítorí bí ó ti jẹ́ obìnrin yìí àwọn ọkùnrin ńlá gbogbo ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ rẹ̀ dì bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Apẹẹrẹ fún àwọn òbí ní èyí. L Murby jẹ ọ̀rẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá, o fi ìwà rẹ̀ fà wọ́n mọ́ra, ó jẹ́ àpẹẹrẹ pé ènìyàn dúdú àti ènìyàn funfun lè jẹ ọ̀rẹ́ ara wọn. Ọ̀gá Ilé-Ẹ̀kọ́ gíga ní Gbóbì ni ọkùnrin náà ti jẹ́ rí, ṣùgbọ́n lónìí, o ń ṣiṣẹ́ ní ibib ti wọn ti ń tẹ ìwé ní ilẹ́ Gẹ̀ẹ́sì. Ṣùgbọ́n, ìwà kìí fi oníwà sílẹ̀, agódóńgbó inú ẹtu ń bá ẹtu lọ. Ọgbẹ́ni Murby ń ti ìgbéga dé ìgbéga ní ibi iṣẹ́ rrẹ̀. Àpẹẹrẹ ni èyí fún gbogbo wa. Ọ̀gbẹ́ni D.R.G Gwynne- Jones ni ọ̀gá Ile Ẹ̀kọ́ gíga ti ìjọba ní Ìbàdàn tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní iṣẹ́ olùkọ́. Ìgbà tí ọkùnrin yìí dé, ọdún méjì ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń lò, ilé tí ó wà fún ìlò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò ju ìba díẹ̀ lọ. Lónìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń lo ọdún mẹ́rin, ilé pọ̀ lọ bẹẹrẹ fún iló wọn. Bẹ́ẹ̀ ni bí nǹkan bá ti ń tóbi tó ni iṣoro rẹ ń tóbi tó ṣùgbọ́n, Gwynne-Jones borí ìṣoro tírẹ̀ patapata. Lóòótọ́ ó mọ ìwé dáadáa, a sì máa ṣe ètò daadaa, bẹ́ẹ̀ ni a máa ṣíṣọ́ bí o ti yẹ, ṣùgbọ́n ohun pàtàkì tí ó ti ọkùnrin náà lẹ́yìn jù ni ti Ọlọ́run tí ó gbà gbọ́. Àpẹẹrẹ ni èyí fún ìwọ àti èmi, bí a bá fẹ́ kí orílẹ̀ èdè wa yìí máa ti ibi gíga dé ibi gíga a kò gbọdọ̀ sàìfi ara ti Ọlọ́run Ọba. Eléyìí ló mú kí ẹ̀rí ọkàn Gwynne-Jones lágbára tó bẹ́ẹ̀ nítorí mo ti báa lò rí mo sì rí i pé kì í fẹ́ kí òun ṣe nǹkan sí ẹnikẹ́ni tí ẹ̀rí ọ̀kan òun yóò fi ddá òun lẹ́bi. Ẹ máṣe gbàgbé eyí ẹ̀yín ènìyàn wa. Revd. M. J. Adé Ṣíjuwádé ọ̀gá mi. Kò sí ọjọ́ kan tí mo ń rántí Revd. Ṣíjuwádé tí ọkàn mi kò ń súre fún un. Lábẹ́ rẹ̀ ni mo ti kọ́ ṣe iṣẹ́ olùkọ́ kékeré; ṣùgbọ́n láìsí ìmọ̀r[sn ọkùnrin yìí, láìsí ìwé rẹ̀ tí mo yá tí mo kà, láìsí àtìlẹ́yìn rẹ̀, n kò lè tó ẹni ti ó ń wọ Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga ní òde Ọ̀yọ́; láìsí dé ilé ẹ̀kọ́ yìí, n kò lè tó ẹni ti ń kọ́wé fún enikẹ́ní láti kà rárá. Mo dúpẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀yin ọgá ilé ìwé ní ìlẹ̀ Yorùbá fún bí ẹ ti ṣe ń lo gbogbo àwọn ìwé mi tẹ́lẹ̀ rí, mo dúpẹ́ pẹ̀lú lọ́wọ́ ẹ̀yín ti ẹ ń yàn ìwé fún iló àwọn ọmọ náà. Ṣùgbọ́n ẹ máṣe rò pé èmi ni ẹ̀ ń ṣe ìwọ̀nyí fún, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ẹ ń ṣe é fún ìran ìran ọmọ wa. Èrò ti èmi pàápàá ni pé ki ń sa ipá mi tó bí ó ti yẹ láti lè mú kí àwọn ọmọ ilé ìwé wa lè máa fẹ́ láti ka ìwé ní èdè wọn, ìdí rẹ̀ sì ni èyí tí o fi jẹ́ pé bí ọmọ kan ba ti bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé wọ̀nyí, yóò fẹ́ kí òun mọ ibi ti ó gbẹ́yìn sí, ìgbà tí ọmọ kan ba rí i pé Ìrìnnkèrindò wọle dé, yóò fẹ́ kí òun lè mọ ohun gbogbo tí ó wá ṣe. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo yín o, bí ẹ sì ti ń ti àwọn ìwé mi wọ̀nyí lẹ́yìn yìí, Olódùmarè ti gbé akeǹgbè ìbùkún, ti yóò tú lé orí gbogbo yín káríkárí. D.O Fágúnwà. Ìfihàn Ìrìnkèrindò wọlé dé Ìbẹ̀rẹ̀ irin àjò sí òkè ìrònú ti ń bẹ́ nínú igbó elégbèje Alábàápàdé Ẹlẹ́gbárá Ìlú àwọn Èdìdàrẹ́ ní ibì tí Òmùgọ́díméjì ti ń ṣe ọba wọn Òmùgọ́diméjì gorí oyé Ṣọ̀pọ̀nná gbé òmùgọ́dimejì lọ Ẹbora ìgbéraga – ìbánújẹ́ àti Ahọ́ndiwúrà ìyàwó rẹ̀ A fi oju wa rí ọ̀run àpáàdì Wèrédìran ti ń gbé ilé Òmùgọ̀parapọ̀ Ìgbéyàwo Irìnkerindo pẹ̀lú àbúrò olókun iwin inu omi Ìlú ìtaǹjẹ-ènìyàn Ogun ibodè igbó elégbèje ÌRÌNKÈRINDÒ WỌLÉ DÉ Ayé kún fún ibùgbé ìyanu, Ọba bí Ọlọ́run kò sí, Olódùmarè ní n ṣe alákòóso ohun gbogbo ti ń bẹ ní òde ayé àti òde ọ̀run. Ìyanu ni ayé pàápàá jẹ́: ayé kún fún ènìyàn ẹlẹ́sẹ̀ méjì àti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin, ejò afayàfà àti alágẹmọ tí Olódùmarè wọ̀ ní onírúurú aṣọ. Òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, òòrùn àti òṣùpá, àwọsánmọ̀ àti erùpẹ̀ ilẹ̀, gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ìyanu.Bákan náà ni ọ̀rọ̀ sísọ lásan yìí jẹ ìyanu, èeyí ti mo sì gbọ́ ní ijọ́sí ni mo ni ki n bá yín sọ lónìí, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn. Bí mo sì ti ń fẹ́ sọ fún yín yìí, mo fẹ́ ki ẹ jẹ́ kí ó wọ ibi kọ́lọ́fín agbárí yin lọ, kí ẹ̀yìn tí ẹ n gbọ ọ̀rọ̀ yìí, fi ọ̀rọ̀ náà ṣe oúnjẹ, àti pàápàá ẹ̀yin ọmọ ilé ìwé, kí ẹ gbádùn rẹ̀ bí ọbẹ adìẹ pàtàkì, tí gbajúmọ̀ obìnrin se, tí o dín tí ó gbẹ tíkẹ́tíẹ́. Lọ́gànjọ́ oru ọjọ́ kan báyìí ni mo déédéé gbọ́ òjò bẹ̀rẹ̀ síí’kù nígbà tí mo sì dìde ní ibùsùn mi ti mo yọ ojú wo òde, mo rí gbogbo àyíká, ó ṣókùnkùn dudu, bẹ́ẹ̀ ni àkókò òṣùpá ni, àfi bi ẹni pe àwọ̀sánmò ti pinnu lọ́kàn rẹ̀ pé òun kò ní tanná fún ènìyàn mo. Àwọn adìẹ sùn lọ tantan, afẹ́fẹ́ tútù rọra ń fẹ́ ]awọn èkúté ń jẹ ẹ̀rún oúnjẹ láàrin àgbàlá, bí ènìyàn kò bá fetí sílẹ̀ tán kò lè gbúròó ẹnu wọn, ṣùgbọ́n òwìwì ń kígbe lẹ́ẹ̀kọọkan, mo sì gbóhùn èlúlu, bẹ́ẹ̀ ni àdán fẹ́rẹ̀ fi ìyẹ́ gbá mi lórí, nítorí òru ni àkókòo ìgbádùn fún ẹranko náà. Bí mo ti ń wo òde ni imọ̀nàmọ́ná bù lẹ́ẹ̀kọọkan, ibi tí n kò bá sì rí tẹ́lẹ̀ rí, ìgbà tí imọ̀nàmọ́ná bá bù báyìí èmi a rí wọn. Nígbà tí ó ṣe tí mo bẹ̀rẹ̀ síí ronu, n kò mọ ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ síí sọ̀rọ̀ sí ìtà tí mo ni, “Ayé yìí kò mà dọ́gba o, ibi ti àgbẹ̀ ti ń jẹ onírúurú oúnjẹ nínú ahéré oko, ni aláàárù ti ń wa gaàrí mu káàkiri ojú ọ̀nà, ibi tí ọba ti ń jókòó lórí ìtẹ́ ni tálákà kò lè jókòó lórí àga, ọlọ́gọ́rùn-ún àpò ń káàkiri inú ayé bẹ́ẹ̀ ni ẹni ti kò rí tọ́rọ́ jẹun náà ń rìn kiri, àkókò tí àwọn ẹlòmíràn bá ń jó tí wọ́n ń yọ̀ ayọ̀ ńlá àwọn ẹlòmíràn a máa sọkún wọ́n á kún fún ìbánújẹ́ gidigidi. A! ọgbọ́nb Olódùmarè ta ìmọ̀ ènìyàn yọ.” Bí mo ti ń sọ̀rọ̀ báyìí, àfi ìgbà tí ẹnìkan déedée dá mi lóhùn ní ẹ̀gbẹ́ ògiri ilé mi, ó ni, “Bẹ́ẹ̀ ni, máṣejẹ́ kí eléyìí yà ọ lẹ́nu, ìwọ ọ̀rẹ́ mi ojú fèrèsé, bí nǹkan kò bá rí bẹ́ẹ̀ olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè ìbà wà ni ìtẹ́lọ́rùn, wọ́n ìbá dúró sí ojú kan bí adágún omi, ni ọ́jọ́ tí ẹnìkan bá ti wí pé ibi ti òun dé ní inu aye yìí tó, ìgbádùn olúwarẹ̀ dé òpin, ẹni tí ó wà ní òde ayé tí kò mùra ìlọsíwájú dàbí òkú láàrin alaàyè, bí ayé bá kún fún ayọ̀, ọmọ ènìyàn kò ní mọ àti kọ ìbànújẹ sílẹ̀ bí ayé bá kún fún owó, ọmọ ènìyàn kò ní mọ ipò tí tálákà wà, bí ayé bá kún fún ìṣẹ́gun, ọmọ ènìyàn kò ní mọ̀ bí a ti ń yọ̀ nígbà tí a bá bórí ìṣòro. Nítorí náà, ìwọ ọ̀rẹ́ mi ojú fèrèsé, ti inú Ẹlẹ́dàá yé Ẹlẹ́dàá kí ó tó dá ènìyàn bí ó ti dá a. Ẹ̀rù bà mí nígbà tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, kí Olódùmarè gba ni lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ àìròtẹ́lẹ̀ ti ń dá ni lóhùn lọ́gànjọ́ òru. Bí ọkùnrin náà ti ń fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni imọ̀nàmọ́ná bù tí mo wo ibi ti ọ̀rọ̀ náà ti ń wá, mo rii, ó lóṣòó gọ́ú sí ẹ̀bá ogiri ilé mi; mo rii, ó wọ ẹ̀wù péńpé bí ẹ̀wù ọdẹ, ó gbé ìbọn kan tì sí ẹ̀gbẹ́ ogiri. Eléyìí kò yé mi, ǹjẹ́ kí n la ẹnu kí n bèèrè ohun tí ń wá, ṣe ni òjò ńlá bẹ̀rẹ̀ tí ọkùnrin náà sì kan ìlẹ̀kùn ilè mi, ó ni, “Jọ̀wọ́ ṣílẹ̀kùn fún mi, ọ̀rẹ́ mi,” èmi náà bá ṣí i fún un. Ìgbà tí ó wọlé tán ti mo rí i ni mo mọ̀ pé ènìyàn pàtàkì ni, nítorí ojú olè yàtọ̀ sí ojú ọmọlúàbí, ọ̀rọ̀ ẹnu olè yàtọ̀ sí ti ọdẹ aperin. Mo kí i òun náà sì kí mi dáadáa, mo gbé aga fún un, ó jókòó, èmi náà jókòó lé àga kan mo kọjú sii. Bí mo ti ń jókòó ní ó bẹ̀ mí pé ki n fún òun ní omi mu, mo bá dìde mo bu omi fún un. Lẹ́yìn tí ó mu omi tán mo tún wa jókòó, ibi ti mo sì ti ń pète kì n béèrè bí mo ti ṣe déedée ríi ni ọ̀gànjọ́ òru ni òun náà bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ í sọ ó ní: “Ohun gbogbo ti ń bẹ ní òde ayé ni ó ni ìdí wọn: gbongbo ni ìdí igi; orísun ni ìdí omí; ẹyin ni ìdì àkùkọ- bí o ti ṣe déédéé rí mi lákòókò yìí kò sàìní ìdí pàtàkì kan. Èmi ni ọkùnrin náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìrìnkèrindò tí ń gbá ilé Alárìnkiri. Ọjọ́ pẹ́ tí mo ti ń wá ọ kiri, k[po sí ibi ti mo saláì wá ọ dé ni òde ayé yìí, nítorí kí bàbá mi to ṣe aláìsí ó ti wí fún mi pé kí n wá ọ̀nàkọnà láti rí ọ ki ń tó kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ki ń sọ nǹkan tí ojú mì ti rí sẹ́yìn fún ọ, nítorí kí ìwọ bà kéde rẹ̀ fùn àwọn olùgbé inú aye, eléyìí nì lè mú àǹfàní bá àwọn ọmọ ènìyàn kí wọn fi ọgbọ́n kun ọgbọ́n inú wọn. Òní yìí ni ẹnìkan tó tọ́ka ilé rẹ hàn mí tí mo fi wá ṣe báyìí rí ọ. Èmi pibà sì ti wọlé kí o tó rí mi ṣùgbọ́n n kò fẹ́ wọlé láàrin òru, bẹ́ẹ̀ ni ààrin òru ni mo dé ilé rẹ. Nítorí náà inú mi dùn púpọ̀ láti mọ̀ ọ́ lónìí. Kí Olódùmarè dá ẹ̀mí sí, rírí tí mo rí ọ yìí ti fi hàn mi pé ọ̀rẹ́ pàtàkì na a máa jẹ́ fún ara wa. Nítorí kí á tilẹ̀ wí pé a ti mọ ara wa tẹ́lẹ̀ rí ni, o kò lè gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀ jù bi o ti gbà mi yìí lọ. Mo dúpẹ́ o.” Báyìí ni ọkùnrin náà sọ, nígbà ti o sì parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ tèmi mo ni, “ọ̀rẹ́ mi, Ìrìnkèrindò, ìwọ ni mo ṣe báyìí rí! – Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọba. Ọjọ́ ti pẹ́ nísisì yìí tí mo ti ń gbúròó rẹ, mo sì ti ń ṣe àníyàn ki n lè mọ̀ ọ́ ṣùgbọ́n a kò bá ara wa pàdé. Mo ti gbọ́ bí o ti lọ sókè sódò ni òde ayé yìí tí o ń wá ọgbọ́n kiri àtti pe bí o sì ti jẹ wí pé bàbá rẹ fẹ́ràn rẹ ti o sì tọ́jú rẹ bí bàbá tíí tójú ọmọ. Òkìkí ìwọ pàápà’ti kàn jákèjádò ayé, ṣùgbọ́n ayọ̀ kún ọkàn mi lónìí wí pé a ojú rí ara wa. Nípa èyí tí o wí, kékeré ni èyí nì, ṣùgbọ́n jẹ́ ki a fi gbogbo ìyókù dọ̀la, nígbà tí ilẹ̀ bá mọ́ n ó mú àwọn ǹnka tí mo ffi ń kọ̀wé, n o sì kọ ohun tí o ba ń fẹ́ sílẹ̀ fún ọ. O kú àbọ̀, o kú ìrìn náà.” Báyìí ni mo sọ fún ọkùnrin náà, níwọ̀n ìgbà tí ó sì ti jẹ́ pé gbogbo ilé ti sùn tán bámúbámú, tí o jẹ́ p�� èmi nìkan ló kù tí kò sùn nínú ilé wa, èmi ni mo lọ fi ọbẹ̀ ra iná tí mo wá oúnjẹ fún un. Lẹ́yìn ìgbà tí ó fún un ní aṣọ bíboora lẹ́yìn eyí a kí ara wa ó dọ̀la èmi náà wọ iyààrà mi lọ. Àtètè sùn làtètè jí, èmi ni mo jí kẹ́yìn nínú ilé wa ní ọjọ́ kejì. Ìgbà tí a jẹ́un àárọ́ tán, mo bọ́ sí ibi tábìlì mi, mo kó àwọn ohun ìkọ̀wé jọ, mo sì pè é kí o jókòó tì mi kí ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ fún mi. Òun náà bá bẹ̀rẹ̀ ó ni: “Ìwọ ọ̀rẹ̀ mi, nǹkan ti ń ó bá ọ sọ yìí, máṣe gbàgbé láéláé, fi í sí ìpamọ́, gbogbo nǹkan ti ń bẹ ní òde ayé gbáà ni ó ní ìgbẹ̀yìn wọn: ìgbẹ̀yìn òwúrọ̀ ni ọ̀sán, ìgbẹ̀yìn ọ̀sán ni alẹ́; ìgbẹ̀yìn ènìyàn ni ikú; ìgbẹ̀yìn oúnjẹ ni orí ààtàn; ìgbẹ̀yìn ìgbà òjò ni ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, ìgbẹ̀yìn odò gbogbo ti ń bẹ nínú ayé kò sí ju òkun lọ. Bẹ́ẹ̀ ni ìwà ènìyàn ni ìgbẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí ó bá soore fún ọmọnikejì rẹ̀ ń gbin eso ìwà sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ tí ó bá máa ká èso ìwà, ojú ìkà ènìyàn yóò máa pọ́n kankan. Ìgbẹ̀yìn ẹni ti ń la ọwọ́ ni iyì, ṣùgbọ́n ẹ̀tẹ́ ni ìgbẹ̀yìn aláhun. Ẹni tí ń láwọ́ wà nínú gbajúmọ̀, ọwọ́ lílà kò le sọ ni di tálákà láéláé, nítorí àṣíi’rí ẹni ti ń lawọ́ kò le tú bí ayé kéré bí kò ju akèǹgbè lọ, ṣùgbọ́n, mọ̀ dájú pé ìnákùná yátọ̀ sí ọwọ́ lílà, nítorí onínàákúnàá ni ẹni tí ó sọ orí ara rẹ̀ nú tí o n fọnka sí ibi tí kò yẹ, àbámọ̀ ni ìgbẹ̀yìn irú ẹni bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n síbẹ̀ náà, onínàákúnàá tún ní ìgbádùn tirẹ̀ lọ́tọ̀, onínàákúnàá lè jẹun sí inú ara rẹ̀, ṣùgbọ́n aláhun a máa gbé ọbẹ̀ ọjọ́ mẹ́wàá lé iná a tún máa fi omi si i. Gbogbo owó tí o ti ń ná láti àná tí mo ti dá yìí jọ mi lójú gidigidi, ṣùgbọ́n nǹkan tí ò ń gbìn sílẹ̀ yìí, o ko ní sàà ka èso rẹ lọ́jọ́ kan. Mo dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá, kí Olódùmarà ṣe wa ni ọ̀rẹ́ ara wa di alẹ́ o.” Nígbà ti ọkùnrín náà dákẹ́ ọ̀rọ̀ i sọ mo fèsì fún un, mo ní: “Ìrìnkèrindò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ gidigidi. Kò sí bí a ti le ṣe ifa kí ó má hùwà èkùrọ́, kò sí bí a ti le ṣe ẹni ti o ń ká[kiri ẹ̀yìn odi kí ọgbọ́n rẹ̀ má ta ẹni tí kò kúrò lójú kan yọ. Mo dá ṣaṣa àgbẹ̀, ọ̀bùn ará ìlú ni. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ fún ọ lóru àná, ó pẹ ti mo ti ń gbúròó rẹ nítorí àti ajá àti ẹran a máa wí nípa tìrẹ pé, ‘Ọlọ́gbọ́n ni Ìrìnkèrindò i ṣe.’ Ìdí rẹ̀ tí mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún ọ̀rọ̀ tí o sọ ni èyí, afooresúníiṣe kún inú ayé, wọ́n dàbí paramọ́lẹ̀ láàrin àwọn ọmọ ènìyàn. Ǹjẹ́ ìwọ mọ̀ pé ẹni tí o wà nínú ìdààmú owó tí a yá lówó tún lè padà kí ó wí pé a yá òun nítorí a jẹ́ amùsùwà ni ! Síbẹ̀ irú àwọn wọ̀n-ọn nì pọ̀ nínnú ayé suu. Wọ́n dàbí òkúta kọ̀bìtì sí ojú ọ̀nà àwọn èrò ẹ̀yìn. Wọ́n ti ba iwájú jẹ́, àwọn tí ó bá ti bá wọn pàdé lẹ́ẹ̀kan kò níí fẹ́ ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ mọ́. Ṣùgbọ́n ìyànjú mi ni èyí pé, kí á má tì tirí ẹni búburú hùwà búburú, nítorí pé bí a bá wí pé kí a bẹ́gi a lè bẹ́ ènìyàn, bí a bá wí pé kí a fi oore ṣíṣe sílẹ̀ pátápátá, alè dá àwọn ọmọlúàbí lórí. Kí ní kan ṣa ni, a kò gbọ̀dọ̀ màa ṣoore bí òmùgọ̀, kí a máa so ẹ̀wọ̀n góòlù mọ́ ẹlẹ́dẹ̀ lọ́rùn, ẹni tí ó bá mọ iyì wúrà ni kí a ta wúrà wa fún. Ọ̀rọ̀ púpọ̀, irọ́ ló ń mú wá, ọ̀rọ̀ mi kò ní gùn gbọ̀ọ̀rọ̀, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí o moore ṣùgbọ́n ko tíi sí nǹkan tí mo ṣe fún ọ rárá, bí a bá fi ọ́ wé ogunlọ́gọ̀ àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ti de sàkání ilé wa.” Lẹ́yìn èyí, ọkùnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ síí sọ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ gan-an ó dáhùn ó ni: “Èmi ni Ìrìnkèrindò ti ń gbé Ilé Alárìnkiri Ìbátan ni èmi àti Àkàrà-Oògùn tí ó wá ní ijọ́ssí jẹ́, ẹgbẹ́ la si jọ jẹ́ pẹ̀lú. Bàbá mi ni ẹni ti ń jẹ Oyińdayépọ̀ tí ó dúró gẹ́gẹ́ bi Mọ́gàjí ni Ilé Alárìnkiri. Oyińdayépọ̀ wá lọ fẹ ìyá mi tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹni-ayé tí wọ́n bí sí ilé àwọn Àkàrà-Oògùn. Àkókò ìgbà tí àwọn Àkàrà-oògùn fi ń múra àti lọ sí òkè láńgbòdó gan-an ni bàbá mi rán mi lọ sí ìdálẹ̀ kan ní ijọ́sí. Inú ìyá mi, Ẹni-ayé, kò dùn sí ọ̀ràn náà nítorí ó fẹ́ ki n bá àwọn èrò òkè láńgbòdó lọ, èmi náà pàápàá sì fẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé bàbá mi fẹ́ wí pé dandan ki n lọ sí ibib tí òun rán mi, kò sí ohun tí èmi àti ìyá mi lè ṣe. Àbúrò mi kan báyìí tí ó lọ sí ìdálẹ̀ tí kò fẹ́ wa sílé mọ́ ni bàbá mi ni ki n lọ mú wá. Àbúrò mi yìí, kìí ṣe ọmọ ìyá mi, àbúrò bàbá mi obìnrin nni ó bí i, ó sì jẹ́ ọmọ líle. Nígbà tí mo máa kúrò nílé, bàbá mi pè mí sí yààrá, nígbà tí mo sì dé ọ̀hún tán o ní ki n súnmọ́ oun, mo sì súnmọ ọ, lẹ́yìn èyí ó fi ọwọ́ kọ́ ni lọ́rùn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ i sọ ó ni: “Ọmọ mi, Ìrìnkèrindò, mo fẹ́ sọ fún ọ lónìí pé ko sí ènìyàn náà nínú ayé yìí tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ju bí mo ti fẹ́ràn rẹ lọ. Ìdi rẹ̀ ti n kò si tíìi fi fẹ́ pé kí o bá àwọn ẹgbọ́ rẹ lọ sí òkò Láńngbódó yìí pin sí ọ̀nà méjì: lọ́nà kín-ín-ní, ọ̀ràn àbúrò rẹ yìí wà lọ́kàn mi, n kò fẹ́ kí ọmọ náà lọ ṣe báyìí sọ orí ara rẹ̀ nù sí ìlú onílùú, lọ́nà kejì, mo fẹ́ kí ojú ìwọ pàápàá là sii: nítorí ẹni ti ń gbé aabà oko ọgbọ́n abà oko nìkan ni yóò ni; ẹni ti ń gbé ìletò, ọgbọ́n ìletò ni yóò ni, ṣùgbọ́n ẹni tí o bá ń là kàkà láti dé ibi púpọ̀ ní ilé ayé yìí, ojú olúwarẹ̀ yóò là ju ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ. “Ṣùgbọ́n, ọmọ mi, sràn ìdálẹ̀ ṣòro. Ẹni tí ó bá ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò olúwarẹ̀ ti gbé àpò ìyà ka èjìká, nítorí ẹni tí ó ti ń sùn lórí ibùsùn ńlá lè di ẹni tí kò ń hanrun lórí ilẹ̀ pẹpẹ, ẹni tí o ti ń fi ẹ̀dọ̀ ẹran jẹun lè di ẹni tí kò rí nǹkan wa gaàrí mu, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí kò tó àbúrrò olúwarẹ̀ lè máa búu kí ó máa ṣépè fún un. Bí ìwọ bá bẹ̀rẹ̀ síí rí nǹkan wọ̀nyí, ronú rẹ dáadáa, kọ ìwọ̀sí tí ó bá yẹ ní kíkọ̀, sì rọ́jú gba èyí tí ó bá yẹ láti gbà mọ́ra. “Máṣe gbagbe ohun gbogbo tí mo bá ọ sọ wọ̀nyí ìwọ ọmọ mi. Kí Ọlọ́run má kọ, àtúnrí, bí Olódùmarè kò bá kọ àtúnrí, a jẹ́ pé n ó tún ffi ojú mi rí ọ, ṣùgbọ́n ikú kìí dá ọjọ́, bẹ́ẹ̀ ni àrùn kìí dá o ṣù, Ẹlẹ́dàá ló mọ ọjọ́ àtisùn ẹni. A kìí mọ, bí o ba dé tí o bá sì gbọ́ pé mo ti kú, máṣe ba ara jẹ́, ṣu òṣùká pàtàkì kí o gbé ẹrù mi bí ọkùnrin. Ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ tí ó bá sì kù, tọ́jú ìwà rẹ, máṣe bá ojú kòkòrò ṣe àjọpín, nítorí ojúkòkòrò ti lu òfin kẹẹ̀wá Olódùmarà, òun dàbí ọ̀mùtí ènìyàn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ lọ mọ ìlú Èkó, tí o wọ reluwé, nígbà tí ó dé ibi tí à ń pè ní Ìdó, ó sọ̀kalẹ̀, ó kọjú sí Èkó, nígbà tí o sì dé o ń afá tí ó wà lórí omi ọ̀sà, o ń wo ìhín wo ọ̀hún, kò fi ojú sí ibi tí ó ń lọ, nígbẹ̀yìn, ó dúró, ó yọjú lórí afá, o tún ṣe, ó gun orí irin gíga tí wọ́n fi mú afá dúró, ó ń rẹ́rìn-ín lẹ́yìn náà, ó doríikodò, o ń fì dùgbẹ̀, ibi tí o ti ń fì dùgbẹ̀, ọwọ́ já, ó tàkìtì, ó di inú odò ẹja ríi, ẹja gbée mi ẹranko ńlá tún rí ẹjà, ẹranko ńlá ggbé ẹja mi, ejò ńlá mìíràn tún rí ẹranko, ejò ńlá tún gbé ẹranko mi, ẹja inú òkun wá bá ẹja inú ọ̀sà seré, ó rí ejò, ó tún gbé ejò mi, nígbà tí ó padà dé inú òkun, ó ti sanra, ẹja mìíràn tún rìí, ó tún gbé e mì, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ àwọn apẹja rí ẹja ńlá yìn, wọn pa á, wọ́n wọ́ ọ sí òkè, wọn mú ọ̀bẹ wọ́n la inú ẹja. Bẹ́ẹ̀ ni wwọ́n la inú ẹja tí wọ́n tún bá ẹja, ti wọn tún la inú ẹja tí eọ́n bá ejò, tí wọ́n la inú ejò tí wwọ́n bá ẹranko, tíi wọ́n la inú ẹranko tí wọ́n bá ẹja, tí wọ́n la inú ẹja tí wọ́n ba ọ̀mùtí ènìyàn tí ó ku giliti bí olójúkòkòrò tí o ń lẹ́pa ohun ìní ọmọnìkejì rẹ̀ tí ó sáré tí ó sáré títí tí ó fi ojú gún igi. Ssọ́ra nípa ojúkòkòrò, máa sá fún un, ó búru ju májèlé lọ. “Ọ̀rọ̀ mi kò ní jù báyìí lọ, mo fi ọ́ sí abẹ́ ìtọ́jú Ọlarun ọba, Ẹlẹ́dàá rẹ yóò máa bá ọ gbé ẹrù rẹ, Olódùmarè yóò taari bìlísì síwájú, Ọlọ́run yóò gbà ọ lọ́wọ́ àwọn abínúkú ẹni, bí o sì ti ń lọ, o kò ní bá eléṣù rìn, o kò ní bá akó-tirẹ̀-bá-tẹni ṣe àjọpín, Olódùmarè yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ àgbákò, o kò ní bọ́ sọ́wọ́ tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kùn, o kò ní pàdé ìjaǹbá, o kò sì níí rìn lọ��jọ́ tébi ń pa ọ̀nà láéláé. Ó dìgbà o, ó dìgbà o. Ó dìgbà, ọmọ mi.” “Báyìí ni bàbá mi sọ, nígbà tí ó dákẹ́ èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ i sọ mo ní: À! Bàbá mi, bí ẹ ti sọ̀rọ̀ jú, ẹ dẹ́rù bà mí lọ́pọ̀lọpọ̀, bí ikú bá jẹ́ aláàánu kò gbọdọ tíì ṣe bẹ́ẹ̀ mú yín lọ. Gbogbo ayé yín, èmi lẹ fi sìn. Gbogbo ohun ìní yín, èmi lẹ fi tọ́jú, kò sì sí nǹkan tó kù lóde ayé yìí tí ẹ kò fi kẹ́ mi. Amodi ní ìjọ́sí ń kọ́:- ọ̀nà wo ni n bá fi wà lóde ayé lónìí bí kò bá sí ẹ̀yín? A! Àmọ́di ńlá tí ó ń fẹ́ pa mí! – Tí òtútù ń pa mí,tí òógùn ń bò mí, igbá àyà mi rí gelete, inú mi ri ringinndin, ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi ri jèkètè, eegun àyà mì ri kẹẹrẹ, orí mi ri palagun, egungun ìhà mi hàn ketekete, iṣan ara mi ri wọ́gọwọ̀gọ bí gbòǹgbò ojú ọ̀nà, ojú mi ri kuọkuọ bi eléèku, ẹsẹ téru, irun orí mi dàbí irun ara ajá eléèku, ẹsẹ mi rí tín-ín rín bí ṣaṣara ọwọ̀, ara mi ń wá rìrì bí àlòkù mọ́tò, mò ń mì fúkéfúké bí rọ́bà kẹ̀kẹ́ ara mi sì ń funfun bí ara aláboyún obìnrin : ìbànújẹ́ dé bá àwọn ará ilé wa, wọn ń sá kiri gọ́lọ́gọ́lọ́ bí ẹja inú omi, àwọn ènìyàn wa doríkodò bí ìmọ̀ ọ̀pẹ, ìyá mi ń rìn ká tìrònútìrònú, ilé wa sì dákẹ́ minimini bí ọ̀gànjọ́ òru. Ẹ̀yin bàbá mi, ẹ bẹ̀rẹ̀ sií wádìí ọ̀ràn yìí, nítorí ẹ kò mọ irú àìsàn tí ó déedéé kọlu mi, ẹ kò mọ irú ohun tí ó dé bá mi, yálà òkè-ilẹ̀ ni, wárápá ní, ibà ni, làkúrègbé ni, ọlọ-inú ni, aràn-àyà ni, ẹ̀yyìn dídùn ni tàbí ìgbẹ́-ọ̀rìn ni – gbogbo ìwọ̀nyí kò yé yín, àfi ìgbà tí ó wu Olódùmarè tí o fi oníṣègùn tòótọ́ hàn yín ni mo tó di ẹni ti ń ṣiré kiri. “Kí ni èmi ha tíì ṣe fún yín, ẹ jọ̀wọ̀ ẹ máṣe ronú ikú, bàbá mi: ẹ jẹ́ kí ń ṣísṣẹ́ kí n di ẹni ti ń lówó lọ́wọ́ ki n ra agbádá ńlá ki n gbé e fún yín, ki n fi dàńdógó pàtàkì bọ̀ yín lọ́rùn, ki n ṣe fún yín bí ọmọ tí í ṣe fún bàbá. Eléyìí ni ọ̀rọ̀ tí mo lè sọ fún yín, mo ṣetán láti lọ sí ibi tí ẹ rán mi, ẹ jẹ́ ki n lọ sílé kí n lọ máa múra.” “Báyìí ní mo sọ tí mo sì lọ sí ọ̀dọ̀ ìyá mi. Ìgbà tí ó di ọjọ́ kejì mo kó ẹrù mi mo kọjú sí ojú ọ̀nà, mo n lọ. “Fún odidi ọjọ́ mẹ́ta tí mo ti kúrò ní ilé, ọkàn mi kò kúrò lára bàbá mi, ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ síí mú ọkàn kúrò ní ilé mò ń ronú ibi tí mo ń lọ. N kò lè ka ohun tí ojú mi rí tán ki n tó dé ọ̀hún nítorí n kò ì tíì rin irú ìrìn bẹ́ẹ̀ rí. Ojú ọ̀nà náà jẹ́ ojú ọ̀nà tí àwọn apànìyàn ti máa ń ṣe ọdẹ ènìyàn kiri, ṣùgbọ́n n kò nìkan rrìn rárá, bí n kò sì ti nìkan rìn yìí náà, a bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà tó ìgbà mẹ́ta kí á tó dé ọ̀hún. Ní àkókò kan báyìí, méjìlá ni àwọn ọlọ́ṣà pa nínú wa. “mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ rẹ̀ mo dé ibi tí àbúrò mí wà lẹ́yìn oṣù kẹta tí mo ti kúrò ní ilé. Ṣùgbọ́n bí mo ti dé ọ̀hún ni ẹni ti mo wá lọ ti gbọ́ pé mo dé, ó sì sá bá oko lọ, mo wá àbúrò mi títí n kò rí i, nígbà tí ó pẹ́ ṣa mo gbúròó rẹ̀ pé ó wà lóko, mo sì fi ènìyàn ṣe ènìyàn wọ́n mú mi lọ. Ọlọ́run sì wá bá mi ṣe é wí pé ní ọjọ́ tí mo dé oko náà ẹ̀yìn ni ó kọ sí mi, kí ó sì tó yí ojú padà, mo ti sáré sí i, mo dí ì mu. Nígbà tí ó wo ojú mi, ó dùn ún, ṣìgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ tí ó ní sí mi kò kúrò níbẹ̀, Ó yípadà, ó dọ̀bálẹ̀ ó sì kí mi dáadáa. Èmi náà kíi, mo sọ oríkì síi, lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ibi ti o ń gbé ó sì wá oúnjẹ fún mi. “Lálẹ́ ni mo tó sọ ohun tí mo bá wá pàtàkì fún un, mo sì bá a wí púpọ̀ pé ohun tí o ṣe kò dará. Kí a ma sa ba ọ̀rọ̀ náà gùn lọ títí, nígbà ti o tó bí oṣù kan tí mo ti dé ìlú náà, èmi àti àbúrò mi múra, ó di ilé. “Oṣù keje ti mo ti kúrò ní ilé ni mo tó padà dé, lọ́jọ́ kẹta tí bàbá mi sì kú ni mo dé ilé bí wọ́n ti sin òkú rẹ̀ tán gan-an ni. “Ìwọ ọ̀rẹ̀ mi, díẹ̀ ló kù kí ikú bàbá mi sọ mi di wèrè; fún odidi ọ̀sẹ́ mẹ́ta n kò mọ̀ bí ayé ni mo wà bí ọ̀run ni. Nígbà tí ó di kùtùkùtù ọjọ́ kan mo lọ sí ibojì bàbá mi, mo sọkún sii, mo ké lóhùn arò, mo ni ‘Ayé mi nìyí, bàbá mi, mo fi ọ́ sílẹ̀ ní ènìyàn, mo bá ọ ni ilẹ̀pa! Bàbá mi tí mo fi sílẹ̀ tì yípadà ó di ibojì! Ikú ti mu akíkanjú lọ! Ikú ti mú ènìyàn pàtàkì lọ! Alábàárò mi ti lọ! Ta ni ń bá fi inú hàn bí kò se bàbá mi! Ta ni ha kù bí aláfẹ̀yìn tì mi! Ta ní kù bí Olùdámọ̀ràn! Ta ni kin wọlé tọ̀ kin jẹun! Ta ni ki n wọlé tọ̀ ki ń sọ̀rọ̀ ẹ̀dùn ọkàn! Ta ni ki ń bá sọ̀rọ̀ lọ́gànjọ́ òru! A! Ikú! Ìwọ adánìlóró ẹ̀dá! Kí ni mo fi ṣe ọ́! Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, ìwọ ni ọ̀tá ogunlọ́gọ̀ ohun ẹlẹ́mìí tí Olódùmarè sọ lọ́jọ̀ sí orí ilẹ̀ ayé. Ìgbẹ̀yìn ewéko inú igbó, ikú ni; ìgbẹ̀yìn ejò afàyàfà, ikú ni; ìgbẹ̀yìn ẹyẹ ojú ọ̀run, ikú ni; ìgbẹ̀yìn àwọn ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin, ikú sì ni pẹ̀lú. Ọlọ́kàn líle ẹ̀dá ni ikiú jẹ́, kò ní àánú ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni kìí pinnu kó bojú eẹ̀yìn lẹ́ẹ̀kan. Kí a sọkún kí ojú fọ́ kò kan ikú, kí á gbára sánlẹ̀ títí kò yíi lọ́kàn padà, kí á wọ aṣọ dúdú kò ṣe nǹkan fún un. Ikú kò náání ẹbọ, kò bìkítà fún ṣìgìdì, bẹ́ẹ̀ ni ońdè àti òrùka kò ṣe é ní nǹkan. A! Ikú, kí ni ìwọ ha ṣe ni ọjọ́ ìgbẹ̀yìn rẹ! Múra, pa ilẹ̀ mọ́, máa dúró de ìdájọ́ ní ìgbẹ̀yìn ayé, àwọn ẹ̀dá alaàyè yóò mú ọ wá sí ìdájọ́ níwájú Olódùmarè ní ọjọ́ náà, eṣinṣin lásán yóò ro ẹjọ́ mọ́ ọ, èèrà yóò jẹ́rìí gbè ọ́ lẹ́sẹ̀, o kò sì níí rí ọ̀rẹ́ láàrin ènìyàn àti ẹranko: nítorí ìwọ ti ba onírúurú iṣẹ́ ọwọ́ Olódùmarè jẹ́, ìwọ ti gé ayé àwọn ẹja kúrú, o ti ba ìgbádùn àwọn kòkòrò jẹ́, ekòlò aláìmọ̀kan kiò sì kúrò lọ́wọ́ pàsán rẹ. Ọ̀pọ̀lọ àti akèré, ìgbín àti ìjàpá, àdán àti òwìwì, èkúté àti òkété, òjòlá àti àjànàkú – gbogbo wọ̀nyí ni yóò gbógun tí ọ́ ní ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ. A! Ikú, ìwọ ẹ̀dá aláìlàánú, mo fi ọ sílẹ̀ fún Ọlọ́run ọba.” “Báyìí ni mo wí ní tèmi tí mo kúrò ní ibojì bàbá mi tí mo wá sí ilé. Wọ́n ṣe òkú náà dáadáa, nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò fi ojú rí òkú náà kí wọ́n tó sin ín, síbẹ̀ àwọn àbúrò mi tí ó wà ní ilá wi fún mi pé àwọn ọmọlẹ́bí mú aṣọ wá ni oríṣìíríṣìí láti fi dìí, àti wí pé wọ́n pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran. Èmi pàápàá bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbọ̀n ẹ̀kọ ní ilé wọ́n sì lu ìlù fún ọjọ́ púpọ̀ ní ilé wa. Emi náà ṣe òkú bí ipá mi ti mọ, ṣùgbọ́n bí mo ti náwó tó, ọkàn mi kò kúrò lára bàbá mi, bí mo bá sì ń rẹ́rìn-ín lójú báyìí, ìbànújẹ́ á bo ìsàlẹ̀ inú mi bí ìkùùku. Bàbá mi ti pín ogún sílẹ̀ kí ó tó kú, ńitorí náà kò sí àríyànjiyàn nípa èyí nì. Wọn ìbá sì ṣú ìyá mi lópó fún ọ̀kan nínú àwọn ará ilé bàbá mi. Ṣùgbọ́n ìyá mi kọ̀, ó ni òun kò fẹ́ ẹnikẹ́ni mọ́ lóde ayé, òun ó jókòó nínú ilé bàbá mi kí òun máa tọ́jú wa. Èmi ni àkọ́bí, ìgbà tí bàbá mi sì kú yìí ni mo tó wá mọ̀ pé ohun tí àwọn àgbà ń fi ara gbà kìí ṣe kékeré, àti pé ẹrù asáa’jú wúwo ju irin lọ. Ohun gbogbo ti n kò ṣe rí ni mo di ẹni tti ń ṣe, èyí tí kò kàn mí rí di tèmi pàtàk[pi, mo di ẹni tí ń parí ìjà fún àwọn ará ilé wa. “Láti ọjọ́ tí ọ̀fọ̀ ńlá yìí ti ṣẹ̀ mi, n kò yé lá àlá rí bàbá mi, àfi bí ẹni pé ó wà láyé ni, èyí tí ó sì wá jọ mí lójú jù pátápátá ni pé, nígbà tí mo bá rí i lójú àlá n kò níí rántí pé o ti kú mọ́, a sì dàbí ẹni pé ó wà láyé ni. Lọ́jọ́ tí mo bá ti lá àlá báyìí, jíjí tí mo bá jí ẹkún ni mo máa ń sun. “Lẹ́jẹ́ kan mo ríi ó wọ ẹ̀wù agbádá dáradára kan báyìí, ara rẹ̀ sì dàbí ara ọmọ kékeré, ó lé wà gidigidi. Ó gbé dígí kan báyìí lọ́wọ́, ó sì fi hàn mi o ní ki n wo inú rẹ̀. Nígbà tí mo wò ó, mo rrí ojú ọ̀nà kan tí ó tóbi, tí ó gbòòrò tí o sì ń dán, apá ọ̀tún àti apá òsì dàbí ẹni pe idẹ ni wọ́n fi ṣe ojú ọ̀nà náà ní ìpẹ̀kun ọ̀nà náà mo rí ilé kan tí ó lẹ́wà, tí ó bàbí aafin ọba. Ṣùgbọ́n kí ènìyàn tó dé ibib dídára yìí, Olúwarẹ̀ yóò kọjá ọ̀nà burúku kan, mo sì rí àwọn ẹranko búburú gbogbo tí wọ́n dúró sí etí ọ̀nà búburú náà, tí wọ́n ń sọ́ ọ. Nígbà tí mo wo dígí náà dáadáa, bàbá mi bi mi ohun tí mo rí, mo sì sọ fún un. Lẹ́yìn náà, ó dáhùn ó ní, ‘Ayé rẹ ni ìwọ ń wò o ni, ìyà yóò jẹ ọ́ ní ìsáájú, ayọ̀ jẹ́ tìrẹ nígbẹ̀yìn, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ba ara rẹ jẹ́ lákòókòo ìyà, yóò ṣòro kí ayọ̀ pigbẹ̀yìn tó dé ọwọ́ rẹ.’ ‘Báyìí ni bàbá mi sọ lójú àlá fún mi, oyíndayépọ̀ Ọkùnrin, bí ó sì ti wí bẹ́ẹ̀ tán ni mo tajì. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, lẹ́yìn òkú bàbá mi, bí mo ti múra tí mo ń fẹ́ lọ sí òde kan báyìí ni mo déédée’rí ìránṣẹ́ ọba tí ó wọlé wá bá mi. Lẹ́yìn tí a sì kí ara wa tán ni ó wí fún mi pé gba ni ó ránṣẹ́ pé ki n wa fi ojú kan òun ní wéréwéré. Eléyìí yà mí lẹ́nu nítorí n kì í dé ilé ọba tẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ọ̀ràn tí mo dá, ṣùgbọ́n bàbá mi a ti má lọ sí ààfin lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kí ó tó di pe títán dé bá a, nítorí òun àti ọba ìlú wa ti ń ṣe ọ̀rẹ́ tẹ́lẹ̀ kí ó tó di pé onítọ̀hún gun orí oyè. Mo wí fún oníṣẹ́ tí ọba rán wá wí pé kí ó máa lọ síwájú dè mi, àti pé mo ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀, lẹ́yìn èyí, mo yi aṣọ mi padà: mo wọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ sí ìsàlẹ́, mo wa wọ tógò mi titun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dá lé e, lẹ́yìn èyí ní ni mo wa gbé ẹ̀wù agbádá ẹtù bàbá mi mo kìí bọ ọrun, mo sì mu ṣòkòtò ẹtù pẹ̀lú mo wọ̀ ọ́, mo wá dé fìlá abetí-ajá sán-ányán mi kan báyìí mo ta á hanha. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe òrùka góòlù kan, mo fii sí ọwọ́ òsì mi sí ọmọ ìka tí ó dúrò sí ipò kerín sí àtàǹpàkò mi. Lẹ́yìn náà ìyá mi wá mú ìbòrùn àrán rẹ̀ tuntun ó sọ ọ́ lé èjìká mi, mo sì tún wá mú sálúbàtà kékeré kan báyìí tí a fi awọ ejò ṣe mo kìí bọ ẹsẹ̀, mo so aago tí mo rà tí ìdálẹ̀ bọ̀ mọ́ ọrùn ọwọ́ mi òsì, mo mú ọ̀pá kan bàyìí tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rà lọ́wọ́, mo sì wá mú ọmọdé kan lẹ́yìn, mo kọ orí sí ilé ọba, mo ń lọ. Bí mo ti ń rìn lọ inú èmi náà ń dùn, yíyẹ́ tí wọ́n sì ń yẹ́ mi sí, àfi bí ẹní pé mo jù báyìí lọ. Ogunlọ́gọ̀ àwọn tí kìí tíí bìkítà fún mi ni wọ́n ń dọ̀bálẹ̀ tí wọn ń wí pé, ‘kẹ́ ẹ pẹ́, kẹ́ ẹ pẹ́, tí èmi náà sì ń kí wọn, tí mò ń ṣe, ‘ọọkú’ bí àgbàlagbà. Òmíràn nínú àwọn obìnrin ilé wa tí wọ́n ń ta ọjà lóde a wá síwájú mi wọ́n á kúnlẹ̀ wọ́n á tú gèlè wọn, wọ́n á máa fi orí balẹ̀ wọ́n á máa yẹ́ mi sí. “Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún mi nígbà tí mo yọ sí ọba tí ó sì dìde lórí ìtẹ́ lẹ́sẹ̀ kan náà tí ó wọ inú iyààrá rẹ̀ ṣùgbọ́n nígbà tí ó wá pẹ́ díẹ̀ tí ó padà dé ni àwọn ìjòyè rẹ̀ wí fún mi pé yíyọ tí mo yọ ní inú ẹ̀wù ẹtù tí mo wọ̀, mo jọ bàbá mi tó bẹ́ẹ̀ tí orí ọba fi wú, àti wí pé nítorí èyí nì ni ọba ṣe wọlé tí ó lọ sọkún nítorí kò gbọdọ̀ sọkún lójú gbangba. Nígbà tí ó dé tí ó jókòó lórí ìtẹ́, èmi wà lókèèrè nígbà tí ó jókòó tán, ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ i sọ ó ni: “Súnmọ́ hùn-ín, ìwọ Ìrìnkèrindò ọmọ mí, mo Súnmọ́ iwájú ìtẹ́, mo dọ̀bálẹ̀, ọba sì tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ ó ní; “Ìrìnkèrindò, èmi ni mo pè ọ́, o kú ìnáwó òkú bàbá rẹ, o kú àsẹ̀hìndè, kí Ọlọ́run jẹ́ kí ẹ́yìn rẹ̀ dára. Ó yà mi lẹnu bí bàbá rẹ ti ṣe ṣe bẹ́ẹ̀ kú nítorí ní kété ìgbà tí ó fi máa kú, ó wá sí ọ̀dọ̀ mi, ara rẹ̀ sì le dáadáa nígbà náà, a tilẹ̀ sọ̀rọ̀ tí ó pọ̀, àfi ìgbà tí ó sì tó ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n mú ọ̀fọ̀ rẹ̀ wá bá mi! – ikú rẹ̀ náà dún mi lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí oyíndayépọ̀ kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ lára mi, kkìí fi ọ̀ràn mi ṣiré, bí ó ti wà ní ilé rẹ̀ nì, kìí ṣe kí ó ma wá bẹ̀ mí wò ni ààfin lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tórí ìwọ̀nyí ni mo sì ṣe pe ìwọ ọmọ rẹ̀, Ìrìnkèrindò, lónìí wípé kí o má jẹ́ kí orúkọ ilé yín bàjẹ́ o. Ní ọjọ́ tí bàbá rẹ wá sí ìhín gbẹ́yìn, ó kó ó rò, bí ó ti jẹ́ pé ó ń ṣe sí òun, tí ó ń hùwà ọmọ dáadáa, tí ó fẹ́ràn òun dé góngó tí òun náà sì fẹ́ràn rẹ. Ó wí fún mi pẹ̀lú bí ó ti jẹ́ pé gbogbo ọgbọ́n imì òun, òun kò fi ọ̀kan pamọ́ fún ọ, ó sì tún wí fún mi pẹ̀lú bí ó ti ṣe jẹ́ ohun ẹ̀dùn ọkan rẹ, ìwọ Ìrìnkèrindò pé o kò lè bá àwọn Àkàrà-oògùn lọ sí Òkè Láńgbòdó tí wọ́n lọ láòpẹ́ yìí, nítorí ibib ti òun rán ọ, àti pé nígbà tí o bá ti ibẹ̀ dé, ọkàn rẹ yóò túbọ̀ gbó láti ṣe bí àwọn ẹgbẹ́ rẹ ti ń ṣe. Nísisì yìí wàyí, Ìrìnkèrindò; ���̀ràn mìíràn ti dé ilẹ̀ o, bẹ́ẹ̀ ni bí bàbá rẹ bá wà láyé, òun ni n bá rán ni iṣẹ́ náà kí ó lọ ṣeé fún mi. Eléyìí náà ni yóò sì fi hàn gbogbo ènìyàn irú ọmọ tí ìwọ yóò jẹ́, yálà bí ó bá ni lè tó ẹrù bàbá rẹ ẹ gbé, tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ ni Oyińdeyépọ̀ bàbá rẹ kìí ṣe kékeré ọkùnrin. Iṣẹ́ tí mo ń fẹ́ rán ọ náà nìyí, mo fẹ́ kí o wá ṣe asáájú àwọn ọ̀dọ̀ mìíràn, kí ẹ wa lọ sí Òkè Ìrònú, ti ń bẹ nínú Igbó Elẹ́gbèje, kí ẹ wá lọ ká èso igi Ìrònú fún mi wa. Igi Ìrònú ni ó fún ìlú náà lórúkọ, abamì igi ni igi Ìrònú, bàbá mi sì ti ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi kí ó tó di pé títán dé báa, tí èmi wá gun orí oyè. Bí ènìyàn bá gbin igi náà sí orí omi ní ìlúkílùú ẹnikẹni tí ó bá mu nínú omi ibẹ̀ yóò di ọlọ́gbọ́n pátápátá. Bẹ́ẹ̀ ni kí ni gbòǹgbò ìgbéga ayé pátápátá? Mo ṣe bí ìrònú ni. Àìronú níí’mú kí ènìyàn jalè, ti ń mú kí ènìyàn ṣèké, tí ń mu kí ènìyàn ṣáá tá ọmọ nìkejì, tí ń mú kí ènìyàn rẹ̀ ọmọnìkejì jẹ, ìrònú ni ó wà ni ìdí ẹ̀rọ mọ́tò, òun ni gbòǹgbò reluwé, òun ni ọmọ-ènìyàn fi ń fò lójú ọ̀run, ìrònú ni pàtàkì ohun ìjà oníṣègùn, òun ni ó wà ní idi egbòogi, paríparí gbogbo rẹ̀, bí ènìyàn bá wà tí ó wí pé kò sí nǹkan tí Olódùmarè lè ṣe, aláìronú ni. Agbára ìrònú pọ̀, òun ni ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin àwọn ọmọ ènìyàn àti àwọn ọmọ ẹranko. Nítorí náà, Ìrìnkèrindò, ìwọ ọmọ Oyíndayépọ̀, bá mi wá èso igi ìrònú lọ.’ Báyìí ni ọba sọ, mo sì fetísílẹ̀ mo gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà tán pátápátá, nígbà tí ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, mo dáhùn mo ni: Kábíyèsí, kí adé pẹ́ lórí, kí bàtà pẹ́ lẹ́sẹ̀, mo gbọ́ gbogbo bí ẹ ti wi, orí ni alákòóso ara, ọba sì ni olórí ìlú, ẹ̀yin ni olórí àwa. Bí ọwọ kò sí ti gbọdọ̀ ṣe àfojúdi sí orí, tí ẹsẹ̀ kò gbọdọ̀ wí pé òun kò sí lábẹ́ ààbò rẹ̀ ni n kò to ẹni ti ń ṣe orí kunkun sí yín. Kábíyèsí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ láti òní lọ pé kìí ṣe ẹni tí ó bá fẹ́ ìyá ẹni nìkan ni bàbá ẹni, kìí ẹni í ó bá sì jẹ́ ìyàwó bàbá ẹni nìkan níí jẹ́ ìyá, baba ẹni lè jẹ́ ọ̀kan, ìyá ẹni lè jẹ́ ọ̀kan, bàbá ẹni lè jẹ́ méjì, ìyá ẹni sì lè jẹ́ méjì, wọ́n lè ju méjì lọ pẹ̀lú bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣàì rí elòmíràn nínú òde ayé tí bàbá rẹ̀ kú ṣùgbọ́n síbẹ̀ tí ó dúró bí aláìní baba, nítorí wí pé, ìbáà ṣe ará ìlà oòrùn, ìbáà ṣe ará ìwọ̀ oòrùn, ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹni ni bàbá ẹni. Kábíyèsí lóòótọ́ ni bàbá mi kò sí nínú ayé mọ́, kí ọba kí ó pẹ́, mo mọ̀ pé ẹ tó baba fún mi. Nípa ti ibi tí ẹ ní ki n lọ, n ó lọ. Ìgbà tí mo bá wí pé n kò lọ, ta ni ki n wí pé o bí mi! Mo fẹ́ kí tajá tẹran jákèjádò ilẹ̀ yìí lónìí mú u kúrò lọ́kàn wọn bí wọ́n bá ní èrò wí pé nítorí Oyíndayépò kú, iná ìfé wa kú, àti nítorí Oyíndayépọ̀ ṣe aláìsí, òṣùpá ilé wa wọ òòkùn, irọ́ mà ni o, kábíyèsí, irọ́ mà ni o, bí Oyíndayépọ̀ bá kú Oyíndayépọ̀ ma sì ń bẹ o. Bàtà tí bàbá mi fi sílẹ̀, mo ti pinnu àti fi ẹsẹ̀ mi sí i, ọ̀nà tí ó ti ń tọ̀ rí, mo ti pinnu àti máa tọ̀ ọ́, bẹ́ẹ̀ ni mo sì ti ṣu òṣùká bàrìbà sílẹ̀ tí n ó fi gbé ẹrù bàbá mi. A! Ó mà ṣe o, Oyíndayépọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ó lọ, baba mi ṣe gudugudu méje fún mi, ó ṣe gudugudu méje fún mi, Oyíndayépọ̀ baba mi, baba mi, baba mi. Kábíyèsí, mo fẹ́ kí ẹ ṣe kiní kan fún mi. Mo fẹ́ kí ẹ yan ènìyàn pàtàkì kan tẹ̀lẹ́ mi kí a yí gbogbo agbegbe lọ kí á kéde ìrìnàjò sí òkè Ìrònú ti ń bẹ nínú Igbó Elégbèje. Ó yẹ kí a sì tètè lọ pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọdẹ ni wọn tì bá Àkàrà-oògùn lọ. Lẹ́yìn eléyìí pẹ̀lú mo fẹ́ kí ẹ yan àwọn ènìyàn Sàǹkòsàǹkò kí ẹ rán wọn lọ sí ọ̀dọ̀ ọba alágbára ibòmíràn gbogbo kí ẹ wí fún wọn nípa ọ̀ràn irìnajo náà kí wọ́n ba à rán àwọn ọdẹ gbogbo jáde. Bí ẹ bá ti ṣe ìwọ́nyí fún mi, inú mi yóò dùn gidigidi nítorí àwọn ọdẹ tí wọ́n ti fi orí mulẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ ni a ó wú jáde. Ìgbà tí a bá ti ṣe ìwọ̀nyí tán èyí tí ó kù kò ní ju kí á dá ọjọ́ lílọ wa kẹ́ ẹ gbó kẹ́ẹ tọ́ o. Báyìí ni mo sọ fún ọba, inú rẹ̀ náà sì dùn sí mi, ó wò mi, ó bú sí ẹ̀rín. Ó ni, ‘A kàn ń sọp pé Oyíndayépọ̀ lágbára ni, eléyìí máa ṣe ju Oyíndayépọ̀ lọ.’ Lẹ́yìn èyí, ọba ni kí wọ́n fún mi ni oúnjẹ, wọ́n sì fún mi. Lẹ́yìn náà ó ní kí wọ́n mú ọtí jáde, wọ́n kó ìgò méjì jáde, ọba pàápàá ni ó sì bu ọtí náà, kì n má fa ọ̀rọ̀ gùn lọ títí ṣá, a parí ìgò méjì yìí ki n tó kúrò ní ààfin, ojú mi ń pọ́n ṣẹ̀ẹ̀, èmi náà ta fìlà mi han ha mo ń ta ráńgọ́ ráńgọ́ lọ. Jíjáde tí mo jáde ṣe ni mo rí onílù tí o ń rékọjá lọ mo bá ní kí ó máa lu ìlú tẹ̀lé mi. O n lu ìlù èmi náà sì ń jó lọ. Àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn ìbátanmi gbogbo ti wọn gbúròó mi ni wọ́n tú jáde tí wọ́n dàpọ̀ mọ́ wa ttí a jọ ń jó lọ, ìgbà tí mo sì fi máa dé ilé, àwọn ènìyàn pọ̀ lọ bẹẹrẹ, mo náwó púpọ̀ lọ́jọ́ yìí, ọjọ́ ìdárayá ni. Nígbà tí ó di ọjọ́ keje ni ọba ránṣẹ́ wá tí o ni òun ti rí ẹni ti òun ó fi lé mi lọ sí ìgbèríko àti pé ki n jẹ́ kí òun mọ ìgbà tí yóò dẹ̀ mi lọ́rùn àti lọ. Mo dá ọjọ́ méje fún ọba. Nígbà tí ọjọ́ pé, èmi àri ìránṣẹ́ ọba múra a yí agbègbè lọ. Bí a tí ń ti ìlú dé ìlú ti ìletò dé ìletò ni wọ́n ń gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò fi ẹnu kan oùnjẹ tí a mú lọ tí a fi dé. Ìrìnàjò wa náà sì nì èrè gidigidi. Àkókò yìí ni a rí abàmì ẹ̀dá kan báyìí mú bọ̀ orúkọ ẹni ti ń jẹ́ Ìbẹ̀ǹbẹ́-Olókùnrùn tí ilé rẹ̀ n bẹ ní ipàlàpálá òkúta. Èmi nìkan ni ó lọ sí ibi tí mo ti ri i. Nígbà ti a dé ìlú kan tí wọ́n wí fún mi pé etí ibẹ̀ ni ọkùnrin náà ń gbé, mo wáa lọ, èmi náà sì múra gidigidi kín tó lọ, wọ́n fi ọ̀nà inú igbó ti o ń gbé hàn mí, ó jẹ́ ojú ọ̀nà oko, nígbà tí mo sì rìn tó bí wákàtí méjì, ẹni ti ó ń ṣe amọ̀nà mi fi ojú ọ̀nà kékeré kan hàn mí tí ó yà ní apá òsì báyìí, ó dàbí ọ̀nà àwọn ọdẹ, ó bá inú igbó lọ. Ó kílọ̀ fún mi kí ó tó lọ pé ki n sọra abàmì ẹ̀dá náà nítorí kí ó má ba à pa mi jẹ nítorí Ìbẹ̀ǹbẹ́-Olókùnrùn ni ó le jéun ju gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ ni orí ìlẹ̀ ayé, òun ni o sì lè mu omi ju gbogbo wọn lọ. Bí o tì wù kí ó jẹun to kò níí yó bí ó sì mu omi odò gbẹ kò ní ní ìtẹ́lọ́rùn, abàmì ẹ̀dá pátápátá gbáà ni. Báyìí ni ìtàn rẹ lọ: kí ó tó kúrò ní òde ọ̀run wá sí aye o ti lọ wọ ẹ̀wù àìkú ni òde ọ̀run láìsí àṣẹ Olódùmarè níbẹ̀, ó jii wọ̀ ni, nígbà tí ẹ̀dá tí ó wà ní ìkáwọ́ ẹ̀wù àìkú kò sí níbẹ̀, orúkọ ẹni ti ń jẹ ògbódògo, bẹ́ẹ̀ ni ó wá sí ilé ayé, bí o si tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn ni o bíi. Síbẹ̀ kò le kú mọ. Ṣúgbọ́n ìgbá tí ó tún dé ilé ayé ìwà rẹ̀ kò fii sílẹ̀. Ní ìsáájú pátápátá. Nígbà tí Olódùmarè ṣẹ̀ṣẹ̀ dá àwọn ọmọ ènìyàn sí òda ayé ti ẹ̀sẹ̀ kò ì tíi sí àwọn ará òde ọ̀run a máa wá ba àwọn ará odee ayé ṣiré wọn a jọ máa ṣe àríyá pọ̀ ni. Ìgbà ‘ti ó di ọjọ́ kan Ìbẹ̀ǹbẹ́-Olókùnrùn ṣe ìpàdé ńlá kan tó o pe ará ayé àti ará ọ̀run wá jẹun, nítorí ẹran tí o rí kò tó, ó pa àrẹ̀mọkùnrin rẹ̀ ó dín in ní ata, nítorí ọtí ti ó rí kò sì tó, ó pa àrẹ̀mọbínrin rẹ̀ o rọ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ si inú ìgò, ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará òde ọ̀run dé, wọ́n mọ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bá ṣẹ èpè fún un pé títí ọjọ́ ìrònúpìwàdà rẹ̀, bi ó ti wù kí ó jẹun tó ko níí yó mọ́, bí ó sì mu omi odò gbẹ kò ní ní ìtẹ́lọ́rùn, ìdí rẹ̀ sì nì yí tí o fi di abàmì ẹ̀dé bẹ́ẹ̀ kalẹ̀ láti ọjọ́ náà wá. Nígbà tí mo bá a, ìbàǹtẹ́ nìkan ni ó sán mọ́ ìbàdí, òkú àgbọ̀nrín méjì ni mo sì bá níwájú rẹ̀ tí ó n jẹ wọn. Ìgbà tí mo dé etí ọdọ rẹ̀ mo pe ògèdè síi kí inú rẹ̀ bà le rọ̀ sí mi, lọ́yìnn náà mo ni: ‘Ìbẹ̀ǹbẹ́-olókùnrùn o kú iṣẹ́ o’- kò tilẹ̀ wo apá ọ̀dọ̀ mi, ounjẹ ti wọ̀ ọ́ lára ṣe ni ó tẹ orí mọ́ oúnjẹ koko, èmi náà sì mú sùúrù díẹ̀ sí i. Ìgbà tí mo ri i pé ó jẹ odidi kan tán mo pè é ni èèkejì: ‘Ìbẹ̀ǹbẹ́-olókùnrùn kú iṣẹ́ o- Òun náà wá wo apá ọ̀dọ̀ mi o fi imú dá mi lóhùn ó ni ; hòo, ó tún bẹ̀rẹ̀ síi jẹ àgbọ̀nrín kejì lọ. Ìgbà tí ó parí àgbọ̀nrín kejì ni o tó wa wò mí dáadáa tí ó dáhùn tí ó wí pé: ‘Kí lò ń wa?’Èmi náà si fèsì mo ní, ìwọ ni mò ń wá, ìwọ ni mo tọ̀ wá gán-an, ọba ìlú mi lo sì ni ki n lọ pè ọ́ wa, nítorí kí a bà jọ lọ sí ìrìn àjò kan. Ní ìrìnàjò yìí, a o dé ìlú kan ní ibi tí àwọn ẹranko ń gbé tí ó jẹ ìlú wọn gan-an, ibi tí ìwọ ó ti máa rí to àádọ́ta àgbọ́nrín fún oúnjẹ àárọ̀, ọgọ́ta ìmàdo fún oùnjẹ ọsán, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ fún ounjẹ alẹ́. Èyí nì ọ̀kan; lọ́nà kejì, a ó lọ sí òkè Ìrònù ti ń bẹ nínú Igbó. Elégbèje ko sì sí àníàní pé bí a bá ti lè ká ọ̀kan nínú èso igi ìrònú jẹ ọ̀nà àti wò ọ́ nínú àìsàn jẹunjẹun yìí kò ní ṣàì yé ni, ohun tí mo bá wá nì yí, Ìbẹ̀nbẹ́-olókùnrìn, ọkùnrin, o kú u jíjẹ, o kú u mímu. “N kò ní jù báyìí lọ. Wéré tí ẹ̀dá yìí ti gbúròó oúnjẹ di dídé lo dìde tí o tẹ̀lé mi tí à ń kó rẹirẹi lọ, bẹ́ẹ̀ náà lo sì ń bá wa kiri títí a fi padà dé ìlú wa. Ìgbà tí mo dé ilé, ìyá mi tún ti ku.” Báyìí ni àlejò mi sọ ìtàn ara rẹ̀, ìgbà tí ó sì fi máa sọ ọ́ dé ibi tí a dé yìí, ilẹ̀ ń ṣu, mo bá dámọ̀ràn pé kí a fi ìyókù sílẹ̀ di ọjọ́ kejì kí á tó tún máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ. Ìbẹ̀rẹ̀ Ìrìnàjò Sí Òkè Ìrònú tí ń Bẹ nínú Igbó Elégbèje N í òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kò pẹ́ púpọ̀ tí mo lọ̀ kí àlejò wa yìí tán tí wọ́n fi wí fún mi pé oúnjẹ ti ṣetán, gbogbo wa lọ sí tábìlì, a jẹun. Iyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé bí ó tiẹ̀ jẹ́ pé n kò sọ fún púpọ̀ nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi nípa ọkùnrin náà tó wọ̀n-ọnnì, síbẹ̀ ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ló ti gbọ́ nípa ọkùnrin náà, kí o sì tó di pé a jẹun àárọ̀ tán lọ́jọ́ náà àwọn ènìyàn ti rọ́ dé ilé wa. Bí a ti jẹun tán ni mo kó àwọn ohun ìkọ̀wé jáde tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, òun náà sì bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ i sọ ó ni: “Ẹyin jànmọ́ọ̀ọ̀, mo kii yín ẹ kú ìjókòó o. Inú mi dún púpọ̀ bí mo ti ri yín yìí. Dájúdájú púpọ̀ nínú yín ni kò mọ̀ mi tẹ́lẹ̀ rí, bí n kò bá sì níi purọ́, ẹ̀yin náà ṣàjèjì sí mi. Lóru ìjẹta mọ́jú àná ni mo dé si ìhín, àti ìgbà tí mo ti dé ni a sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, iṣẹ́ la fi gbogbo àná ṣe, a ṣiṣẹ́ títí ilẹ̀ fi ṣu ni èyí kò sì fún ni láyè àti jáde rárá, bí kò bá sí bẹ́ẹ̀ ni, a bá ti fi ẹsẹ̀ ba púpọ̀ nínú ilé yín. Ẹni ti ó bá rí ọ̀rẹ́ mi yìí, ó yẹ kí olúwarẹ̀ kíi dáadáa, Ọmọlúàbí ni. Láti ìjẹta tí mo ti de síhìn-ín lo ti bẹ̀rẹ̀ síi náwó fún mi, òun àti ìyàwó rẹ̀ kò tilẹ̀ jẹ ki n mọ̀ pé mo kúrò nílée rárá, nítorí náà, mo fẹ́ kí ẹ bá mi dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn dáadáa.” Báyìí ni ọkùnrin náà sọ, àwọn àlejò wọ̀n-ọn nì sì dúpẹ́ lọ́wọ́ mi, lẹ́yìn náà o tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ ó ni: “Mo ti sọ lánà-án bí o ti jẹ́ pé ọba ìlú wa rán mi ní iṣẹ́ wí pé ki n ṣe olórí àwọn ọdẹ pàtàkì ti wọn n lọ sí ìlú pàtàkì kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ òkè Ìrònú níbi tí wọn o ti ká èso Ìrònú lórí igi ìrònú nínú Igbó Elégbèje. Òkè Ìrònú ń bẹ létí odi ọ̀run. Mo wí lánà-án pẹ̀lú bi èmi àti ìránṣẹ́ ọba yi gbogbo àgbègbè lọ tí à ń wá àwọn ènìyàn pàtàkì kiri, mo sì tún wi pẹ̀lú bí a ti ṣe rí abàmì ẹ̀dá kan mú bọ̀ orúkọ ẹni ti ń jẹ́ Ìbẹ̀ǹbẹ́-olókùnrùn ti ó jẹ́ ẹni ti o le jẹun júlọ lórí ilẹ̀ ayé. Mo fẹ́ kí a máa bá ìtàn náà lọ. “Kìí ṣe Ìbẹ̀nbẹ́-Olókùnrùn nìkan ni a rí mú bọ̀. Ọkùnrin kan báyìí bá wa bọ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ kùmọ̀dìran, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn pàtàkì ni, ó jẹ ẹnìkan tí ìṣẹ̀da tirẹ̀ yàtọ̀ gbáà, bí ènìyàn kò bá lùú ní kùmọ̀ dáadáa lẹ́yìn ọrùn ara rẹ̀ kìí le. Ọ̀ràn dandan sì ni pé bí ó bá ti jí ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ẹnìkan níláti nà án ní kùmọ̀ mẹ́fà lẹ́yìn ọrùn, kí o nà án ní mẹ́fà ní ìbàdí kí ó sì kàn án ni ẹ̀sẹ̀ mẹ́fà ni igbá àyà kí ó tó jẹun, bí kò bá sí bẹ́ẹ̀ ara kùmọ́ddìran kò níí le lọ́jọ́ náà, a ní orí ń fọ́ òun a ní inú ń run òun, a sì bẹ̀rẹ̀ síí ṣe bí arúgbó kiri. “Àwọn òbí rẹ̀ ló kúkú jẹ́ kí ó rí bẹ́ẹ̀, ìtàn ọkùnrin náà yóò sì fi hàn yín ohun tí ó jẹ́ kí ìṣẹ̀dá tirẹ̀ kúkú yàtọ̀ tó bẹ́ẹ̀. “Ní ayé àtijọ́, àwọn ẹranko a máa sọ ara wọn di ènìyàn, wọn a sì máa wá sí ọjà láti ra oúnjẹ won á bọ àwọ̀ ara tìwọn sílẹ̀, wọn a bẹ̀rẹ̀ sí í tọr\p ẹ̀yà ara ènìyàn kiri lọ́wọ́ àwọn iwin inú igbó ti ẹ̀yà ara wọn dàbí ti ènìyàn wọn a máa tọrọ lóríṣìíríṣìí ni, wọn á gba apá lọ́wọ́ ẹnìkan, wọ́n á gba ẹsẹ̀ lọ́wọ́ ẹni kejì wọ́n á gba orí lọ́wọ́ ẹnì kẹta, ìgbà tí wọ́n bá to ìwọ̀nyí jọ wọ́n á dàbí ènìyàn gidi gan-an. Nigbà tí ó di ọjọ́ kan, erin wá gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ẹkùn sì wá gẹ́gẹ́ bí obìnrin, wọ́n rí ara wọn, wọ́n fẹ́ ara wọn. Erin tí ó jẹ́ ọkùnrin gba ilé kan ó ń sánwó o ṣooṣù lé e lórí ibẹ̀ ni àwọn méjéèjì sì ti máa ń pàdé lọ́jọ́ mẹ́sàn-án mẹ́sàn-án ọjọ́ ọjà. Àdéhùn wọn kò yẹ̀ fún odidi ọdún kan gbáko èkíní kò mọ̀ pé ẹranko ni èkejì, ó sebí ènìyàn ni kí a ma sa fa ọ̀rọ̀ gùn lọ títí, ẹekùn lóyún fún erin, wọ́n bí Kùmọ́dìran. Ó jẹ́ arẹwà ènìyàn, ó ga, ó sígbọnlẹ̀, ó sì lágbára tó bẹ́ẹ̀ ti n kò tii gbọ́ pé ẹnìkan fi ẹ̀yìn rẹ balẹ̀ níní ìjàkadì rí. Ọwọ́ rẹ̀ gùn, nítorí baba rẹ̀ nì o ti ọwọ́ jọ ṣùgbọ́n yyíyára ìyá rẹ̀ ló mú lóòótọ́ ẹni tí ó bí ni là á jọ, Kùmọ́dìran jọ àwọn òbí rẹ̀ gan-an. Ó jẹ́ ẹni ti o ẹni tí ó mọ ọdẹ i ṣe púpọ̀, nítorí bí ó ti n fi ìbọn pa ẹran náà ni o ń fi ọwọ pa, ti ó tún n fi ẹesẹ̀ pa, nítorí ẹsẹ̀ rẹ̀ tóbi díẹ̀, o fi jọ bàbá rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà rí. Ẹnì kẹta tí o tún jẹ́ pàtàkì tí a rí mú bọ̀ ni ẹni tí oríkọ rẹ̀ ń jẹ Ayédèrú-ẹda ti o ń gbé ìletò kan lẹ́bàá ìlú wa, òun ni o ń fẹ́ obìnrin kan báyìí ti ó ń jẹ Inúdiméjì tí i máa ń gbé ilé Ìbẹ̀rù parapọ̀. Ní àkokò tí a dé ìletò yìoí ní iná kan bẹ́ sílẹ̀ nínú ilé Ìbẹ̀rùàrapọ̀ tí ó jó ilé náà kanlẹ̀ ko. Ṣíbẹ̀ Àyédèrú=ẹ̀dá ṣe ìtọ́jú wa tó bẹ́ẹ̀ ti n kòì tíí rí ẹni ti ó tọ́jú ènìyàn tó bẹ́ẹ̀ rí. lọ́jọ́ tí a dé ibẹ̀ gan-an, àpótí ọti kan ló wá gbé fún ni, ó sì fi màlúù méjì lé e. Lọ́jọ́ kejì, o fi ẹrù iṣu méjìlá ránṣẹ́ pẹ̀lú ṣago ẹmu ogidi mẹ́wàá, ó gbé àpò ìdọ̀họ gaàrí kan, àpó èlùbọ́ méjì, garawa epo mẹ́jọ pẹ̀lú àpó iyọ̀ ńlá kan. Olówó ni ọkùnrin náà ó sì ní tó ilé méjì sí ìletò yìí, ọ̀kan nínú ilé náà lo ń gbé nígbà tí a báa, gbogbi nǹkan ti o fi ń rránṣẹ́ si wa wọ̀n-ọnnì ọkùnrinn kan báyìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ojuayédùn lo ń tẹ̀lé wọn wá, òun ni olórí àwọn to ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ Ayédèrú-ẹ̀dá. “Ìnáwó tí Ayédèrú-ẹ̀dá ṣe fún wa ni àkókò yìí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó sì jọ mi lójú tí mo fi pinnu pé òun ni yóò jẹ́ ìgbá kejì mi nígbà tí a ba n lọ sí òkè Ìrònú nínú igbó Elégbèje. Ẹ máṣe gbàgbé pé lẹ́yìn tí ọba ran awa kí a wá àwọn alágbárta gbogbo lọ sí àgbègbè ìlú wa ó tún rán àwọn mìíràn lọ sí ọ̀nà tí ó jìnà sí ọ̀dọ̀ àwọn ọba ńlá gbogbo. Ìgbà ti àwọn wọ̀nyí máa padà dé, tti ń ṣe ọdẹ ki ìyá mi tó wọlé ọkọ àwọn arìnrìn àjò ti wọ́n ti rin tí ojú wọn ti dá ṣákáṣáká, àwọn arúgbó tí ojú wọn ti rí abàmì nǹkan nínú ayé, àwọn amòye tí ọgbọ́n ti fi agbárí wọn ṣe ibùjójòó, àwọn jagun jagun àti alágbára gbogbo, adáhunṣe àti ẹlẹ́bọlóògùn, gbajúmọ̀ àti bbọ̀rọ̀kìnní, àwọn ọmọ tálákà àti àwọn ọmọ olówó- gbogbo wọn ni wọ́n pé sí ìlú wa; àkókò pàtàkì ni. “Nígbà tí gbogbo wa pada dé pátápátá láti ibi tí ọba rán wa ni ó sọ fún mi pé kí á dá ọjọ lílọ wa a sì dá itadógún. Nígbà tí a dá ọjọ́ tán báyìí, ọba bẹ̀rẹ̀ síi ṣe ìtọ́jú mi ni onírúurú ọ̀nà, ó fún mi ni àpò owó kan láti fi ṣe ìpèsè ìrìnàjò náà, mo di ẹni tti ń wọlé tí ń jáde ni ààfin ọba. Ọwọ́ epo ni aráyé ń ba ni la, wọn kì í bá ni la ọwọ́ ẹ̀jẹ̀, ò ṣì ní ń jẹ ‘Ta ni mọ̀ ọ́’, owo ni ń jẹ́ ‘Mo bá ọ tan’. Nígbà tí àwọn ará ìlú wa rii pé mo ń ṣe bi iré bi iré mo ń di ènìyàn pàtàkì ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ síí wọ́ wá sí ilé mi, ti wọn ń ṣe ọ̀rẹ́ mi, àwọn ìbátan wa gbogbo ti a sì ti sọnù rí ni ọ̀ràn yìí wú jáde tí wọ́n fi ara wọn hàn bí ará ilé mi bí àwọn ẹ̀gbọ́n mi ti ń bbí sii, ni àwọn àbúrò mi ń lé síi, àkókò náà ni mo sì mọ̀ bí bàbá ńlá baba mi ti ṣe ba ìyá ńlá ìyá ẹelòmíràn tan. Ní àkókò yìí n kò wá òògùn tí mo fi ń rii, wọn ń múu wwá bá mi ni: mo ni òrùka idẹ àti ti irin, mo ní òrùka òjé àti ti bàbà, bẹ́ẹ̀ ni onírúurú ońdè ní ń bẹ ní ìbàdí mi: nítorí mo fi awọ erin ṣe ońdèe, mo fi ti ẹkùn ṣe mo sì fi ti ìjímèrè ṣe pẹ̀lú. Mo ṣe ọmọ owú ni àgbẹ̀dẹ mo sì ṣe ẹ̀mú mo rẹ wọ́n ni òògùn mo so wọ́n mọ ìdí mi, mo mú ìwo àgbáńréé, mo sọ ọ di àpótí mo kó òògùn kún inú rẹ̀ bámúbámú. Ọṣẹ òògùn mi kò ní iyr, àgúnmu ko ṣe e kà , mo sín gbẹ́rẹ́ ẹ̀rẹ̀kẹ́, mo sin si àtẹ́lẹwọ́, mo sin sí àtẹ́lẹsẹ̀, mo sín sí ori ọmú, mo sin sí orí ìdodo, mo sín sí ihò imú, mo sín sí ojú ilà àtẹ́lẹwọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀tátèlégbèje gbẹ́rẹ́ ni ń bẹ ní àtàrí mi. Mo ṣe ètùtù títí mo pa ẹsin mẹ́fà, mo pa àgùntàn mẹ́fà ní àgbàlá, ọgọ́ta ewúrẹ́ ni mo sì fi ṣe sàáráa[sí ìkòríta. Mo túbọ̀ múra mo kọ́ ifa mọ́ ifá, mo mọ pàtàkì nínú àwọn odù, mo mọ ìtàn ayébáyé, mo mọ ìjìnlẹ ògèdè, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí mio fẹ́rẹ̀ ẹ bọ́ nibi ti mo ti ń jẹ ataare. Iyààrá kan pàtàkì ni mo fi fún òògùn nínú ilé wa, ọmọkọ́mọ kò gbọdọ̀ ta firi lágbègbè ibẹ̀, àfi ọmọ tí ó bá ro ọkàn tán láyé tí ó fẹ́ lọ fi ọbẹ jẹ ẹ ni ọrun. Nítorí tírà wà ní òkè àjà iyààrá mi, onírúurú ni gbogbo wọn, ọ̀sanyìn olohun kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ wà láàrin àwọn ṣìgìdì, àdó àti atọ́ kò gba òògùn mi mọ́, mo kó ogunlọ́gọ̀ sínú ìkòkò iyààrá mi – àwọn nǹkan wọ̀nyí ti pé sí mi lọ́dọ́ kí ọjọ́ lílọ wa tó pé. “Nígbà tí ọjọ lílọ wa ku ọjọ méje ọba pàṣẹ kí wan lu agogo yíu ìlú ká pé kí gbogbo àwọn ará ìlú wa sí ààrín ọjà ní ọjọ tí a ó bá lọ kí á bà dágbére fún ara wa. Nígbà ti ọjọ́ lílọ pé gọngọ sọ ní ìlú wa, kí ìlẹ̀ to mọ ni gbogbo ènìyàn ti ń wọ́ jáde ti wọ́n sí ti dúró sí ààrinn ọjà dè wá. Gẹ́gẹ́ bí ètò tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀, gbogbo àwọn ọdẹ ti yóò ba ni lọ sí ìrínàjò náà yóò kọ́kọ́ wá sí ilé mi, ibẹ̀ ni a o ti ko ẹsẹ̀ lọ sí ààrin ọjà. Àwọn ọdẹ ti kò ba níí lọ yóò de ni kutukutu wọn ó dúró ni àráádọ́ta ẹsẹ sí ara wọn ní méjì méejì ti wọn kọjú sí ara wọn, ọ̀kan ni apá ọ̀tún ọkan ní apá òsì ojú ọ̀nà tí awa yóò máa gbà rìn kọjá lọ, bí a bá ti ń dé ọdọ ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọdẹ wọ̀n-ọnì àwọn méjì tí wọ́n kọ́jú sí ara wọn, níláti yinbọn sí ojú ọ̀run lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ìgbà tí ọba dé sí ààrin ọjà, a o gbọ́ ariwo ní ilé mi, ìgbà tí a bá sì gbọ́ ariwo ni àwa náà yóò tó dìde. Bí á ti ṣe ètò yìí náà ni a tẹ̀lé e, ìgbà tí ọba dé ààrin ọjà, a gbọ́ ariwo ni ilé wa, àwa ọdẹ sì to ni ẹsẹẹsẹ a tẹ̀lé ara wa ọgbọn-ọn ran kan, à ń lọ, gbogbo wa jẹ́ àádọ́ta. Ìgbá tí a dí mọ́ra tán tí a jáde, o ń wu àwọn ti kò fẹ́ lọ tẹ́lẹ̀ ki wọ́n bá ni lọ. Bí a bá ti dé ọ̀dọ̀ àwọn ọdẹ ti wọ́n wà lójú ọ̀nà wọ̀n-ọnnì, wọ́n á yìnbọn. Nígbà tí a dé ààrin ọjà, a lọ sí ibi tí wọn ti pèsè sílẹ̀ fún wa. N kò ní lè dárúkọ gbogbo wa bi a ti ṣe tò lọ lẹsẹẹsẹ, ṣùgbọ́n n ó ẹni mẹ́sàn-án nínú wa. Èmi ni mo dúró sí ipò kín-ín-ní Ẹni ti ó dórú tẹ̀lé mi ni Ayédèrú-ẹ̀dá ti mo tì sọ ìtàn rẹ̀ sáájú. Ẹnì kẹta ni ọkùnrin kan bbáyìí ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Inúlayéwà tí ó jẹ́ ẹni tí ó gbọ́n púpọ̀ tí ó sì jẹ́ Olókìkí ènìyàn. Kìí ṣe ará ìlú wa, ṣùgbọ́n àna mi ni òun ni ó fẹ́ ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tí ó jẹ́ ìyekan bàbá mì. Ìdálẹ̀ ni ẹ̀gbọ́n mi náà lọ tí wọn fi ri ara wọn, tí wọ́n fẹ́ ara wọn, nítorí náà a ti máa wá sí ilé Alárìnkiri tẹlẹ kí ó to di pe ọ̀ràn Igbó Elégbèje kanlẹ̀ yìí, Inúlayéwà jẹ ẹni ti ó máa n ṣiṣẹ́ káàkiri ẹ̀yìn odi ojú rẹ̀ sì ti rí nǹkan púpọ̀ sẹ́yìn, o ti gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú, o tì gbé ààrin onírúurú ènìyàn, ìyà ti jẹ ẹ́ ebi ti pa á, wọ́n ti di rìkíṣí mọ́ ọ, o ti ṣàìsàn, ó ti jókòó láìrí àga, ó ti dùbúlẹ̀ lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, òùngbẹ ti gbẹ ẹ́ láì rí omi, ó ti dúró ní odidi ọjọ́ láì jẹun, ó ti rìn ní òun nìkan lójú ọ̀nà, ó ti sùn láìrí aṣọ bora òtútú ti pa á, òòrùn ti pa á. Ó sì ti rí ẹgbàágbèje ìwọ̀sí tí ènìyàn ń bá pàdé lẹ́yìn odi. Ẹnì kẹrin ni ẹni ti orúkọ rẹ ń jẹ́ Ewé-ẹ̀yẹ tí ó jẹ́ babaláwo pàtàkì ní apá ìlá oòrùn. Olóògùn bí Ewé-ẹ̀yẹ kò sí àfi bí a bá máa purọ́ tan ara ẹni jẹ, nítorí ọdún mẹ́fà ni o gbé nínú igi Ìrókò ti o ń ṣe babaláwo fún àwọn ẹ̀mi búburú ti ń gbé inú igi. Lẹ́yìn èyí ni ó tún jókòó sínú igbó fún odidi ọdún kan, níbẹ̀ ni ó sì ti rí abàmì ìjímèrè kan tí o fi onírúurú ewé hàn án, tí ó sì kọ ọ ni ìlò wọn. Ewé-ẹ̀yẹ ni ó na iwin dé ibi ti iwin ti ń pohùn réré ẹkún, òun ni ó gba aṣọ lára òkú ti kò tètè lọ sí ọ̀run, ti o ń yọ sí àwọn ènìyàn kiri, a máa gbọ́ ohùn ẹyẹ, a máa gbọ́ ti ẹranko, a sì máa gbọ́ ọ̀rọ̀ tí igi bá sọ sí ara wọn. Òun ni ó gbé iwin ní ìyàwó létí adágún omi tí ó yá owó lọ́wọ́ ọ̀sanyìn tí ó gba ohun ọ̀sìn lọ́wọ́ Èṣù ti ń gbé ìkóríta. Ẹni kaàrún ni ọkùnrin kan báyìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olójú-Májèlé tí i ma gbé eyín erin kiri. Bí ìtàn ọkùnrin náà ti lọ nì yí. Bàbá rẹ̀ iwin ni, ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ ènìyàn ni. Ìyá rẹ̀ jẹ́ arẹwà ènìyàn. Nígbà tí ó wà ní wúndíá tí ó lọ sí oko lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀ ni ọjọ́ kan lákòókò ọdún orò, bí ó ti ń rìn lọ ni ó déédéé gbọ́ tí orò ń ké bọ̀ lẹ́yìn, ó bá sá wọ igbó ó ń bá igbó lọ, bí o bá sì ti ń gbúròó orò ni o ń túbọ̀ ń wọ inú igbó si i, nítorí kí ó má ba à rí oró lójú ọ̀nà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣìnà sínú igbó, nítorí orò ti ń ké kì í ṣe ojú lásán, àwọn iwin ni wọn mú orò jáde kí a má sa fà á gùn lọ títí ilẹ̀ ṣú u sínú igbó. Ibi ti o tí n káàkiri ní òun nìkan ni ó ti bá iwin kan pàdé, ti ó fi inú òkúta ṣe ibùgbé tí ó ní ojú mẹrin, imú méjì, àti ẹnu méjì tí o sì ni ìwo méjì tí ó dábì ìwo àgbáǹkéré ní àtàrí. Ìgbà tí iwin náà rí obìnrin yìí kò ṣe é ní nǹkan kan, ṣùgbọ́n ó mú u sí ọdọ rẹ nínú ihò ó sọ ọ́ si ìyàwó. Nínú ṣí’se bẹ́ẹ̀ ọmọbìnrin náà lóyún, ó bí olójú-májèlé sílẹ̀. Ìwà iwin àti ti ènìyàn kò lè bá ara ṣe déédéé àsẹ̀ypinwá àsẹ̀yìnbọ̀, tọkọtayà yìí jà, ọkọ́ lé aya jade ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ọmọ tí wọn bí kò ti tíì dágbà tó bẹ́ẹ̀, kò lè fi ìyá rẹ̀ sílẹ̀, nígbà tí obìnrin náà sì máa kúrò nínú ihò òkúta ni bàbá rẹ̀ fi eyín erin ta ọmọ rẹ̀ lọ́rẹ títóbi ni eyín erin náà, ó lu ihò láti apá kan dé apá kejì bí ènìyàn bá tì wù ti ibẹ̀ jìnà tó. Ẹni tí o dúró sí ipò kẹfà ni Kùmọ́dìran tí mo ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìsáájú. Ẹni tí ó dúró sí ipò keje ni ọkùnrin kan ti orúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Fìlásayépọ̀ tí o ń gbé filà àràmàdà kiri. Ọkùnrin náà jẹ́ Ìbátán Olójú-májèlé ní ìdí ìyá, ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn iwin pátákí ni bàbá rẹ̀ ṣe nítorí baba rẹ̀ ni àbúrò Olókun tíí ṣe alákòóso omi, ó sì tún jẹ́ aburo Èsìdálẹ̀ tí ó jẹ́ ijoye pàtàkì ní òde ọ̀run. Ọ̀run Àpáàdì ni Filásayépọ̀ dàgbà sí nítorí bàbá rẹ ti fi i fún Èṣù tii ṣe ọba ìbẹ̀ ní kékeré kí ọmọ náà má ba à bàjẹ́, Èṣù sì fi ìyà jẹ ẹ́ gidigidi, ibi iná ìléra ńlá ni Èṣù fi sí kí ó máa fẹ́ iná ní ọ̀run Àpáàdì, eléyìí sì mú kí ojú ọkùnrin náà yípadà kí ó di pupa, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ara rẹ̀ yípadà tí ó di dúdú mọ̀nàmọna. Ìyàlẹ́nu tí ó wá ti ìdí ọmọ náà jáde ni pé ìgbà tí ó pẹ́, apá Èṣù kò ká a mọ́, bí Èṣù bá rán an níṣẹ́ a ṣe èyí tí ó wù ú, bí Èṣù bá rán an kí o yára wá sínú ayé kí ó dá ìjà sílẹ̀ láàrin ọ̀rẹ́ méjì, á wá á sọ wọ́n di ọ̀rẹ́ ara wọn, ìgbà tí Èṣù ba ń jà ọ̀run Àpáàdì á máa wáàsù fún àwọn ọmọ Èṣù. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Èsù kà á sí ẹni burúkú, ó lé e jáde, ìgbà tí òun náà ń bọ̀, Ó pàdé ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀mí ọ̀dọ̀ Olódùmarè lọ́nà, ìgbà tí ó sì kó tí ó rò fún un, inú ẹ̀mí náà dùn ó sì fi filà kan ta á lọ́rẹ, ohunkohun tí ó bá n fẹ́ ni fìlà náà lè ṣe fún un, nítorí iwin ń bẹ nínú filà náà, bí ó bá sì ti sọ̀rọ̀ sí fìlà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, iwin á jáde, ohunkóhun tí ó bá ní kí o ṣe ni yóò ṣe. Ṣùgbọ́n Fìlásayépọ̀ kúrò ni ọ̀run Àpáàdì ó wá sínú ayé o ń ṣíṣẹ́ ọdẹ, ibi tí wọ́n di ọ̀rẹ́ ara wọn ipa kùmọ́dirpan ni o sì tọ̀ dé ìrìnàjò sí Òkè Ìrònú yìí. Ẹnì kẹjọ ni Ìbẹ̀ǹbẹ́-Olókùnrùn tí mo ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún yín tẹ́lẹ̀. Ẹni kẹẹ̀sán ni ọkùnrin kan báyìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìrèké tí ó sọ ijó jíjó di iṣẹ́ ńlá tí ó sọ orin kíkọ di òwò pàtàkì tí o sì fi fèrè rẹ̀ sí ipò ọmọ. Ìyekan ni Ìrèké àti Olóhùn-iyọ̀ tí ó ba àwọn Àkàrà-Òògùn lọ sí òkè-Láńgbòdó ni ijọ́sí, ọkùnrin yìí lè jó ju òkòtó lọ, bẹ́ẹ̀ ni tí ó ba ń fọn fèrè rẹ̀ kí tẹranko tènìyàn máa jó ni. “Nísisì yìí, ẹ ti gbọ́ orúkọ àwọn mẹ́sàn-án pàtàkì nínú wa, n kò ní lè dárúkọ àwọn mọ́kànlélógójì yòókù, nítorí àkókò ń lọ, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ètò wa Olúkúlúkú ló gbé ìbọn lọ́wọ́, àfi Ìrèkè nìkan ni kò gbé ìbọn, o ń fọn fèrè rẹ̀ kí ìrìnàjò wa bà dàbí ìrèkè kí ó gbadùn bí oyin. Nígbà tí àwọn ọdẹ wọn-ọnni dúró sí apá kan, inú ọmọ ènìyàn dùn. Wọ́n tó fi ṣe fọ̀rífọ́rí, wọ́n dúró bí alágbára, ọkàn wọn balẹ̀ bí ẹni tí ó gbẹ́kẹẹ̀lé Olódùmarè, wọ́n le bí akọ òkúta nínú ìpinnu wọn, ọkàn wọn ti hu iyẹ̀ ó fò kúró nínú ilé pẹ̀lú ìfàsẹ́yìn ibẹ̀, ó lọ sí ẹ̀yìn odi ọ̀run. Àwọn ọmọ aráyé wò wọ́n, wọ́n bú sí ẹ̀rín, wọ́n sì kọ́ ọgbọ́n pàtàkì nì láti ara wọn wí pé, ko sí nínú ìwà Olódùmarè pé kí o kọ ìlérí fún àwọn ọmọ ènìyàn àfi bí ohun tí àwọn ọmọ èn[piyàn bá fẹ́ ṣe bá máa jẹ́ fún ìpalára. Ẹni tí ó dá ayé ti ó tóbi bàǹtà banta bí irú èyí, tí ó fi ènìyàn jọba lórí gbogbo rẹ̀, eléyìí nì ti parí oore. Lẹ́yìn tí ọba fi wa hàn àwọn ara ìlú tán tí o sọ̀rọ̀ rere nípa wa ó ni bí mo bá fẹ́ sọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn gbogbo lórúkọ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi, mo lè sọ̀rọ̀. Nígbà tí ó wí báyìí, èmi náà ba bẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ i sọ mo ní: “Mo kí gbogbo yin o, mo kí onílé mo sì kí àlejò, mo ki gbogbo ènìyàn pátápátá, mo kí yín lórúkọ àwọn ẹgbẹ́ mi wọ̀nyí, àwọn arákùnrin gbogbo ti ń lọ si oke Ìrònú, ti ń lọ sínú Igbó Elégbèjè. Àwọn àgbà ti pa á lówe pé, bí o ti wù kí ó pẹ́ tó, ẹgbẹ̀rún ọdún ń bọ̀ wá ku ọ̀la, ọ̀la náà pé lónìí a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọba. Ogboìya onísòwò níí jèrè, hílàhílo ni oníyèméjìí máa bá kiri – kí Ọlọ́run má ṣe wá ni oníhìlàhìlo ènìyàn. Ẹ̀yin ọmọ ìlú mi, bí ẹ ti rí wa yìí, akìí ṣe òmùgọ. Bó ọmọdé bá ṣubú a wo iwájú, bí àgbàlagbà bá ṣubú, á wo ẹ̀yìn. Láti ọjọ́ ti a ti ń bọ̀ ní ilẹ̀ yìí, ǹ jẹ́ báyìí ló yẹ kí ọgbọ́n wá mọ? Bí àwọnn baba ńlá wa bá jí ni isà òkú lónìí ki ni ìbá jẹ́ èrò wọn? Bí wọ́n ti ṣe ń gún iyán láti egbẹta ọdún sẹ́yìn la ṣe ń gún un lónìí, bí wọn ti ṣe ń rokà láti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà oṣù sẹ́yìn la ṣe n ro ọka, bí wọn ti ń kọ ọ̀pẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ ọpẹ kíkọ la ṣe ń kọ ọ̀pẹ, egbòogi tí wọ́n ti mọ̀ a kò mọ̀ ọ́ mọ́, ìgbéraga ti sọni di èrò ẹ̀yìn: ọmọdé ń sọ̀rọ̀ sàka sí àgbàlagbà, ọmọkùnrin kò ka bàbá rẹ̀ sí mọ́, ọmọbìnrin a ró aṣọ ìgbéraga sí igbá àyà, a ní ìyá òun kò jámó nǹkan kan – bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ìwọ̀nyí àìrònú ni. Ìdí rẹ̀ nì yí, ẹ̀yin ènìyàn wa, tí o fi di pé ẹ rí gbogbo wa tí a pinnu lọ́kàn wa pé àfi dandan bí a ti ayé lọ sí ẹnu odi ọ̀run, sí òkè Ìrònú ti ń bẹ nínú Igbó Elégbèjè, ìlú ni Òkè Ìrònú, ó eà lẹ́nu odi ọ̀run, ṣùgbọ́n inú rẹ̀ ni Igi Ìrònú wà èso èyí tí ó le ṣe ìlẹ̀ yìí loore. À ń lọ nítorí egbẹ̀rún ìran ti ń bọ̀ lẹ́yìn, à ń lọ nítorí gbogbo yín. Kò sí nǹkan tí ó dùn mọ inú Olódùmarè rékọjá pé kí ènìyàn mú kí ayé ẹlòmíràn ddi dáadáa, kò sí nǹkan tí ó dùn mọ́ inú Olódùmarè bí i kí ènìyàn jẹ, kí o fún ẹlòmíràn ní ààyè àti jẹ kí ènìyàn mu kí ó sì fún ọmọ ẹlòmíràn ni ààyé àti mu. Ẹni tí kò fẹ́ ki ti ẹlòmíràn dára jẹ́ kìnìhún láàrin àwọn ẹranko, àsá ìdí láàrin ẹyẹ, paramọ́lẹ̀ láàrin ejò, bẹ́ẹ̀ ni orúkọ àwọn ẹranko wọ̀nyí ti bàjẹ́ láàrin ìgbẹ́ sísá ni gbogbo ẹ̀dá alààyè ń sá fún wọn. Mo sì fẹ́ kí gbogbo yín mọ̀ pé bí a ti ń lọ yìí, a mọ nǹkan ti ń bẹ níwájú wa, a mọ̀ pé ẹranko búburú wà lójú ọ̀nà, a mọ̀ pé ejò olóró ń ddúró dè wá, a mọ̀ pé à ń ti ilé ọla lọ̀ bá ebi, à ń ti ilé lọ ba òùǹgbe, a sì ń ti ilé lọ bá ẹgbẹ̀rún ìyà tí yóò jẹ ni. Ṣùgbọ́n kí ni ẹ̀mi ènìyàn? Ẹrọ tí o ń lù kìkì lás��n! Kí ni èrò Ẹlẹ́dàá tí o fi ẹrọ yìí fún ni? Ǹjẹ́ Olódùmarè fún ìwọ àti èmi ni ẹ̀mí yìí fún ìlò ara tiwa nìkan ni? – ó tì o – kìí ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Ẹ̀mí mi wà fún ìlò rẹ, ẹ̀mí rẹ sì wà fún ìlò mi. Ẹlẹ́dàá kò ya àwọn ọmọ aráyé ní ipá, ó ṣe wọ́n ní ọ̀kan ṣoṣo, àgbájọ̀ ọwọ́ ni a fi ń sọ àyà. Pẹ̀lú ayọ̀ ni àwa fi ń lọ lónìí kí ayé ọmọ elòmíràn bà dára. Mo ti gbé inú ayé fún ìgbà díẹ̀, àwọn tí mo bá láyé sì ti sọ fún mi pé, bí ẹni tí ó ń soore tilẹ̀ fi ẹsẹ̀ kọ̀, kò le ṣubú láéláé. ẹni tí o ń wá ìgbéga fún ọmọnìkejì ko ní sí láàrin àwọn èrò ilẹ̀, ìkà kò lágbára níwájú Olóòótọ́, à ṣíírí Onígbèrága kìí bọ̀, ìṣubú onígbèrága dábí ìgbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá fẹ́ igi okó, tí ó wo ìrokò lulẹ̀, tí ó dá ẹka ìrókò, tí ewé ìrókò rẹ̀ sílẹ̀, ttí igi náà sì gbẹ; àsẹ̀yìǹwá àsẹ̀yìnbọ̀ Olú ń hù lára rẹ̀, ó di ààbò fún òkété, ibi ìṣiré àwọn ẹyẹ ibùgbé àwọn ejò, ibi tí aláǹgbá ti ń lé ara wọn kiri nítorí onígbèrága, kò fẹ́ ire ọmọ ẹlòmíràn, o ń fẹ́ kí a rí òun níkan ṣo ṣo. Ẹ̀yin ènìyàn wa, tiyín ni àwọn ọdẹ tí ẹ̀ ń wo wọ̀nyí ń fẹ́, wọn kò fẹ́ ti ara wọn nìkan ṣoṣo. Nítorí náà bí a ti ń lọ yìí, a ki yín ó dìgbóṣe ẹ wò wá kí ẹ tún wa wò, nítorí bóyá eléyìí ni yóò jẹ́ ìgbẹ̀yìn tí ẹ ó ri ẹlòmíràn ń mú wa. Ǹjẹ́ mo kí yín lórúkọ àwọn ẹgbẹ mi, àwọn akíkanjú ènìyàn ti ń lọ sí òkè Ìrònú ó dìgbà o, bí ikú bá pa wá, kí ẹ ṣe òkú wa dáadáa, kí ẹ ṣe òkú wa bí òkú ọlọ̀lá, kí ẹ ṣe ọ̀fọ̀ wa bí ọ̀fọ̀ ènìyàn pàtàkì, kí ẹ má sì ṣe jẹ́ kí nǹkan ìwọ̀í dé sàkání ohun ìní wa – ó dìgbà o. Báyìí ni mo sọ̀rọ̀ fún àwọn artá ìlú wa. Nígbà tí mo parí ọ̀rọ̀ mi, ọba náà tún sọ̀rọ̀ dáadáa nípa wa, lẹ́yìn èyí, a múra à ń lọ. Ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ló sìn wá sí ojú ọ̀nà, ìpínyà náà sì ṣòro gidigidi: ẹlòmíràn ń pòṣé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń mi ìmí ọ̀dùn, ojú àwọn ọmọbìnrìn sì dàbí orísun omi nínnú èyí tí omije ti ń lo ìbòrùn láti fi nu òógùn ti ń ṣàn bí àgbàrá òjò kúrò lára rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn àgbàlagbà kò sí nínú àwọn ẹlẹ́kún wọ̀n-ọnnì, wọn ń pè wá ní òkọ̀ọ̀kan bí a ti ń lọ, wọn ń fún wa ní ìmọ̀ràn, wọn n fi etí kò wá létí, wọ́n sì ń sọ onírúurú ọ̀rọ̀ àṣírí fún ni bí a ti ń lọ. Nígbà tí mo mọ̀ pé gbogbo wọ́n ti lọ tán pátápátá mo wí fún àwọn ẹlẹgbẹ́ mi kí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ kí wọ́n dúró dè mí, lẹ́yìn náà mo yà sí inú igbó ní apa ọ̀tún mi, nígbà tí mo dé ọ̀hún, mo ké pe Olódùmarè pé kí ó jọ̀wọ́ ṣe alátìlẹ́yìn wa bí a ti ń lọ, mo ra ọwọ sí ojú ọ̀run mo sì wí fún Olódùmarè pé, Ṣìgìdì kò lágbára níwájú Ọlọ́run, Àǹjọ̀nnú kò gbọdọ fi ọwọ pa ìdà Ẹlẹ́dàá lójú, ọgbọ́n orí ẹni kò tó gba nì là láìfi ti Ọlọ́run ọba si i. Mo bẹ Ẹlẹ́dàá mi pé bí ti jẹ́ aṣáájú àwọn ọdẹ wọ̀n-ọnnì, kí ó jẹ́ kí n jẹ́ aṣáájú rere. Mo bẹ Olódùmarè kí ó jẹ́ kí n mọ ipò mi láàrin àwọn ọdẹ wọ̀n-ọnnì ki n lè máa ṣe sí Olúkúlùkù bí mo ti fẹ́ kí o ṣe sí mi. “Báyìí ni mo ṣe tí mo kó ọ̀ràn mi lé Ẹlẹ́dàá mi lọ́wọ́, nítorí nínú ohun gbogbo tí ènìyàn lè fi ẹ̀yìn tì ni òde aye kò sí èyí tí ó lágbára bí Ẹlẹ́dàá ẹni. “Nígbà tí mo padà dé ojú ọ̀nà olúkúlùkù t;un ẹrù dì dáadáa, lẹ́yìn náà a gbéra a kọjú sí ọ̀nà wa. “Òkè Ìrònu jìnà púpọ̀, bí ènìyàn bá bá tilẹ̀ dé Igbó Elégbèje tán, Olúwarẹ̀ níláti rìn jìnà dáadáa kí ó tó le dé ìlú náà. Ó súnmọ́ òde ọ̀run ju òkè Láńgbòdó lọ nítorí ọjọ́ mẹ́sàn-án ni àwọn ará ibẹ́ máa ń ná ọjà pẹ̀lú àwọn ará òde ọ̀run. Odò kan báyìí ni ó pín ibẹ̀ níyà pẹ̀lú ọ̀run, gbangba sì nì àwọn ti ń gbé ibẹ̀ máa ń wo ohun tí àwọn ará ọ̀run bá ń ṣe. Bí ènìyàn ba ń tọ odó náà lọ sí apá òkè, nígbà tí olúwarẹ̀ yóò bá fi rìn tó wákàtí mẹ́ta yóò kan odi ńlá kan tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí ààlà láàrin ayé òun ọ̀run. Etí ìbẹ̀ ni ilé Ikú wà, ilé Ikú kò jìnà sí ilé Àrùn ti ń ṣe ìyàwó rẹ̀, bẹ́ẹ̀ nì etí ibẹ̀ náà ni ilé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bàbá-onírungbọ̀n- yẹ́úkẹ́ ẹni tí ń gbé ibi gegele òkúta. “Ọ̀nà Igbo Irúnmọlẹ̀ ni ọ̀nà Igbó Elégbèje. Ìgbà tí ènìyàn bá sì kọjá igbó náà tán tí o fi ìlú àwọn ẹyẹ àti ti ẹranko sílẹ̀ ni olúwarẹ̀ yóò tó rí ọ̀nà náà tí ó bá apá ọ̀tún lọ. Èyí nì ni pé olúwarẹ̀ kò ni dé oríta ọ̀nà òkè Láńgbòdó kí ó tó yà. Olúwarẹ̀ yóò kọjá odò aró ṣùgbọ́n èèm-ejì ni olúwarẹ̀ yóò dá odò ẹ̀jẹ̀ kọjá. Àpèjúwe tí mo ṣe wọ̀nyí yóò fi hàn yín pé ìrìnàjò ti ó léwu ni ìrìnàjò náà, ṣùgbọ́n a kò rí ìyọnu rara, ojú wa kò sì rí nǹkan kan jù bẹ́ẹ̀ lọ títí a fi ibẹ̀ ni ìjàngbọ̀n ti bẹ̀rẹ̀. N kò lè sọ onírúurú nǹkan abàmì ti a fi ojú wa rí nínú igbó burúkú yìí tán, nítorí àwọn iwin ìbẹ̀ pọ̀ gidigidi, bí a sì ti ń lọ ni wọn ń yọ sí wa. Ṣùgbọ́n mo níláti sọ nǹkan kan tí a ri ni nǹkan bi agogo mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ọjọ́ kan. “Ṣe ló déédéé ṣe tí a gbọ́ tí ẹnìkan ń polówó ọjà tí o ń ké lóhùn rara báyìí pé: ‘Ará ìgbó, èrò ọ̀nà, ẹ wá bámi rà á ooo, ọjọ̀ mi pọ̀, owó kékeré ni: wárapá, pọ́nùn mẹta; ṣọpọ̀nná pọ́nùn méjì; ẹ̀tẹ̀, pọ́nùn mẹ́rin; wèrè, pọ́nùn mẹ́fà; orí fífọ́, sílè mẹ́wàá; ẹsẹ̀ dídùn, ṣílè mẹ́fà; oówo, ṣílè kan ; inú rírun, ṣílè mẹ́wàá; sòbìà, pọ́nùn kan; òtútù, tọ́rọ́; làkúrègbé pọ́nùn kan; ìgbẹ́ ọ̀rìn , pọ́nùn kan-àbọ̀; ifọ́n, sísí, kúrúnà tọ́rọ́; ìkọ́, pọnùn kan; ibà, ṣílè méjì; òkè ilọ̀, pónùn méjì; aràn, ṣílè mẹ́ẹ̀dógún abbl... “Bí ẹni tí ó ń polóeó ọjà èèmọ̀ yìí ti ń pa á ni à ń gbọ tí àwọn kan ń pè é tí wọ́n ń rà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ìgbà tí ó sì ṣe, a rí òun pàápàá. Ọmọbìnrin ni, ṣùgbọ́n ó lẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ tí n kò bá irú rẹ̀ pàdé rí, ó ró aṣ\p funfun, ó wọ ẹ̀wù funfun, ó di irun orí rẹ̀ wìnnìkìn winnikin, ó pupa fẹ́ẹ́rẹ́, ṣùgbọ́n ó ní ìyẹ́ méjì ńlá ni apá bẹ́ẹ̀ ni bàtà fàdákà wọ́n dá ẹ̀wù tí ó wọ̀ ní ọ̀nà tí ìyẹ́ lè fi rí àyè yọ jáde, ó wọ bàtà fàdákà, ṣùgbọ́n inú àtẹ tí ó gbé ọjà títà rẹ̀ gbogbo sí, góòlù ni. Nígbà tí a rii, ṣe ni nǹkan náà la gbogbo ara wa já pátápátá tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé apá tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé ẹsẹ̀ tí á kò tilẹ̀ lè la ẹnu wa sọ̀rọ̀ jáde lẹnu. Ṣùgbọ́n òun kọjú sí wa ó ni, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn ènù ni ìránṣẹ́ Olódùmarè, àwọn ẹni ti ń ra ọja mi wọ̀nyyí ni à ń pè ni alátùn-únṣe. ẹ̀yin ọmọ ènìyàn ni ẹ fa àìsàn bá ara yín nínú ayé, Ṣugbọ̀n à! Kò sí ẹda tí Ẹlẹ́dàá fẹ́ràn tí o ta ẹ̀yin ènìyàn yọ, nítorí Ẹlẹ́dàá kò lè fi yín sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà tí àwọn alátùn-úunṣe ba ra àìsàn tí mò ń tà, wọ́n a mú u lọ, wọn á ló fii ṣe igi, nígbà tí àìsàn yìí bá mu igi wọ́n á mú dígí pẹlẹbẹ tí Olódùmarè fún wọn, wọ́n a fi wo kòkòrò ti o ń dá àìsàn náà sílẹ̀ lẹ́yìn èyí, wọ́n á mú kòkòrò náà tọ Ọlọ́run ba lọ. Ìgbà tí Ọlọ́run bá rii, Ọlọ́run á kọ́ wọn ni ọ̀nà à ti fì bá kòkòrò bẹ́ẹ̀ jà a sì fún wọn láṣẹ àti lọ kọ́ ọ sí ìgbá àyà àwọn ọmọ ènìyàn. Ìgbà tí Dókítà pàtàkì bá sùn ní òru tàbí babaláwo àtàtà, àwọn alátùn-únṣe wọnyí á fò lọ, wọn a lọ kọ ọ sí agbárí wọn. Ṣùgbọ́n, ó mà ṣe o, ìgbà tí àwọn oníṣègùn pàtàkì wọ̀n-ọnnì bá jí, tí wọ́n ronú tí wọn rí ìdí àìsàn yìí, wọn kò níí mọ̀ pé iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá àwọn ni. Ìbáṣe pé ọmọ ènìyàn kì í fi ojí idà wọn gbolẹ̀, díẹ̀ ni Ẹlẹ́dàá pàápàá ìbá fi jù wọn lọ, ipò tí ó fẹ fi wọn sí pọ̀, ó fẹ́ràn wọn. Bí ó ti wí báyìí tán, ó fò lọ. Ìgbà tí ó lọ tán ni ara wa tó padà bọ̀ sí ipò tí a tó lè sọ̀rọ̀ tíi a tó lè rẹ́rìn-ín sí ara wa. Ṣùgbọ́n nígbà tí a gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ẹ̀dá pàtàkì náà sọ, ó dùn mọ́ ni nínú, àti pàápàá ní ìbẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wa, a mọ̀ pé Oládùmarè tí ó fẹ́ràn ọmọ ènìyàn to bi óo ti sọ yìí, kò ni jẹ fi wá ssílẹ̀ ní àkókò ìyọnu. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iwin ni a tún ba pàdé lẹ́yìn èyí, ìgbà tí o tilẹ̀ ṣe èrù wọn kò bà wá mọ. A kò rin púpọ̀ nígbà tí a bá ọ̀kan pàdé tí o tilẹ̀ di ọ̀rẹ́ wa gidi, Ìrànlọ́wọ́ ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́. Òun ló wí fún wa pé òun ni ��un yọ Àkàrà-oogùn nínú ìtìmọ́lé Àgbákò, òun lo sì fún wa ní ìmọ̀ràn bí a ó tì ṣe tí a kò fi ní dé ìlú àwọn ẹyẹ ní ibi tí ògòngò ti n ṣe ọba wọn. Ó wí fún wa pé bí wọ́n bá rí ni, wọn ó fi ojú wa rí nǹkan nítorí ohun ti àwọn Àkàrà-oogun ti sẹ si wọn. O fi ọna kan báyìí hán wa, òun ni a sì gbà títí a fi fi ìlú àwọn ẹyẹ sílẹ̀ ní ibi tí ògòǹgò ti ń ṣe ọba wọn. Kò pẹ́ tí iwin yìí fi wá sílẹ̀ tán tí a pàdé àwọn mẹ́ta kan. Nígbà tí a pàdé èkíní, kò kí wa; nígbà tí ó sì rékọjá wa tán ó pòṣé. Nígbà tí a pàdé ẹ̀kejì; o mi ìmí ẹ̀dùn kanlẹ̀, ó wò wá láti òkè dé ìsàlẹ̀, ó ṣe bí ẹni pé ó ń pẹ̀gàn w,a nígba tí a pàdé ẹ̀kẹta ó mọ́ wa lójú, ó pòṣé, ó sì sọ̀rọ̀, ó ni, ‘Àwọn alákọrí gbogbo’ Èyí tí o tilẹ̀ wa bú wa yìí kò pa rárá, ó dàbí kùkùté, nígbà tí mo sì wo ẹnu rẹ̀ báyìí, ó dàbí ẹnu ọbọ, eyín méjì kan tí ó ká báyìí nínú eyin rẹ̀ mú kí eyín rẹ̀ rí kafuru àfi bí ẹni pé wọ́n ṣe ìlẹ̀kùn sí ẹnu abàmì ẹ̀dá náà. Ìgbà tí mo sì ri ì bí àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta ti ṣe, mo fèsì fún èyí tí ó pè wa ni alákọrí, mo ní, ‘orí rẹ alákọrí, àyà rẹ alákọrí, ìwọ ẹbọra abi eyin bí eyín òkété yìí.’ Kí ni iwn gbọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe, ó ni, Mo mọ tiyín bẹ́ẹ̀ ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, ẹ̀yin onisọ́kúsọ, oníròkurò, onírrìnkurìn, oníwàkuwà, oníjẹkújẹ, onímukúmu, oníṣekúṣe, ọlọ́kẹ̀,ọlọ́ṣà, olè, aláìmọ̀kan, aláìmèrò, aláìlágbára, ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwa kì í ṣe ẹgbẹ́ yín? – Kí ni ayé ọmọ ènìyàn já sí? –Ayé kí wọ́n máa purọ́ mọ́ ara wọn !- kí ni ayé ọmọ ènìyàn já mọ́? Ayé kí wọ́n tú àṣírí ara wọn! Kí ni ayé ọmọ ènìyàn já mọ́? Ayé kí wọ́n máa jowú ara wọn! ẹni tí ó bá wà ní ipò gíga wọn kò jẹ́ tìí lẹ́yìn, àfi bí wọ́n ja a tilẹ̀. ẹni tí ó lówó, àwọn ọmọ ènìyàn ko ni bá a wá ọ̀nà bí owó náà ti ṣe máa bí sii, àfi bí wọ́n ti ṣe máa da ojú ọwọ́ rẹ̀ dé ilẹ̀. Ipo ti Olódùmarè fi ọmọ ènìyàn sí, wọn kò mọ̀ ọ́, ẹ̀wù funfun tí Olódùmarè gbé bọ ọmọ ènìyàn lọ́rùn, wọ́n da epo pupa si i, Ẹlẹ́dàá fún wọn ni aṣọ iyì, ṣùgbọ́n wọ́n rìn ní ìhòòhò- ẹ̀yin aláìmoore, ẹ̀yin kò mọ̀ pé òkúta tí ó ga jù yin ni ìgbà ẹgbẹ̀rún, ẹ̀yin a maa fọ́ o, igi tí ó ga jù yín ní ìgbà àádọ́ta, èyin a máa bẹ́ ẹ lulẹ̀, omi òkun bí ó ti tóbi tó ni, ó wà níkàá wọ́ yín, ẹ̀ ń fi ọgbọ́n yín mu erin, ẹ̀ ń fi mú ẹkùn, ẹ sì fì ń mú kìnnìhún ọba ẹranko. Àwa tí a ti mọ ìwà yìn kò bìkítà fún yín mọ́, ìwà búburú yín kò jẹ́ kí ẹ to nǹkan lójú wa. Báyìí ni iwin náà bú wa, bí o sì ti ń sọ̀rọ̀ ni mò ń wo eyín rẹ̀ kíká tí ó mú kí ẹnu rẹ̀ ri foforo. Ìgbà tí o kọ ń buu wa mo ti rò pé bí ó bá parí bíbú rẹ̀, ni a ó bẹ̀rẹ̀ ìjà, ṣùgbọ́n nígbà ti ó fi máa parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, èrì ọkàn mi ti padà nítorì gbogbo ọ̀rọ̀ tí o sọ wọ̀n-ọnnì, kò fi wọn purọ́ mọ àwọn ọmọ aráyé, nítorí eyí, ìgbà tí ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, mo sọ orí kọ́, èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mmi dórikodò, à ń rìn kọ́ńdú kọ́ńdú lọ. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn iwin yìí di ìjà láàrin àwa pàápàá bàyìí ni: ṣe ni a fi àwọn iwin náà sílẹ̀ tán tí ọkùnrin kan báyìí tì à ń pé ni Gọ̀ǹgọ̀ṣú-tàkìtì àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti ń jẹ́ Ìnàkí-gorí-ìtẹ́ bẹ̀rẹ̀ gbé mi tí wọ́n ń bá mi pé n kò sọ̀®ọ̀ fún àwọn iwin náà tó bí ó ti yẹ. Ọ̀rọ̀ náà dùn mi púpọ̀, nítorí nígbà tí a pàdé wọn, minimini ni àwọn ti a jọ ń lọ dákẹ́, ẹ̀rù ń bà wọ́n, èmi tí mo sì tilẹ̀ ṣe ọkùnrin díẹ̀ tí mo sọ̀rọ̀, dípò kí wọn yìn mí, búbú ni wọ́n ń bú mi mo ni, ‘Njẹ́ ìwọ, ìwọ Gọ̀ǹgọ̀ṣú t[kìtí, ìgbà tí a pàdé wọn, ìwọ tó ọ̀rọ̀ i sọ? Hìn-ín? –Dá mi lóhùn, mo ní ìwọ yìí tó ọ̀rọ̀ i sọ? - Ẹ kò rí ẹnu rẹ̀ báyìí.’ Nígbà tí mo wí bẹ́ẹ̀ mo tilẹ̀ rò pé yóò wí pé òun fẹ́ bá mi jà ni, àfi bí mo ṣe ri i ti o ń tún ṣòkòtò rẹ̀ ṣe dáadáa, ṣòkòtò ọdẹ tí ó wọ̀ tí ó padà tí ó wí pé òun ń lọ bá àwọn iwin náà jà nítorí eyí tí mo wí. Gbogbo ènìyàn bẹ̀ ẹ́ títí kò fẹ́ gbọ́. Ṣùgbọ́n ìbá tilẹ̀ gbẹ́ o, bí kò ṣe ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Ìnàkí-gorí-ìtẹ́ tí ó wí pé àfi bí ó padà dandan. Kí a má sa fa ọ̀rọ̀ náà gùn lọ títí, Gọ̀ǹgọ̀ṣú- tàkìtì padà, Ìnàkí-gorí-ìtẹ́ náà sì tẹ̀lé e. Àṣe àwọn iwin náà kò jìnà rárá àfi wéré tí wọn padà tí a bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ igbe Gọ̀ǹgọ̀ṣútàkìtì tí ó ń ké, ‘Ẹ gbà mi o, ẹ wá gbà mi o, ó pa mi o, ó yọ mí lójú o abbl.’- ni a bá yára sáré padà. Ìgbà tí a máa dé ọ̀hún iwin ti yọ ojú Gọ̀ǹgọ̀ṣútàkìtì, wọ́n sì de Ìnàkí-gorí-ìtẹ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, wọ́n fún un lókùn daindanin ṣe ni ó ń ṣẹ́jú pàkò bí ejò ọka. ṣe ni a bẹ àwọn iwin títí kí wọ́n tó dà fún wa, nítorí kò ríran mọ́, ṣe ni à ń fà á lọ́wọ́ kọjá lọ láàrin ìtàkùn àti igi gbogbo tí o kún ojú ọ̀nà wa. Ìgbẹ̀yìn ọ̀ràn ọ̀ǹgọ̀ṣútàkìtì burú púpọ̀, nítorí ìgbà tí àwọn iwin ti yọ́ ọ lójú ni ọkàn rẹ̀ ti kúrò nínú ayé, nígbà tí ó ṣe, ko jẹun mọ́ bẹ́ẹ̀ ni kò mu omi, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó ṣubú lulẹ̀, a gbé e, a fẹ́ òyì si i, ṣùgbọ́n kò gbọ́, ìgbà tí ó ṣe, ó pa ojú dé, a fún ata sii lójú, kò sọ̀rọ̀, a pa ọfọ̀ sii, kò dá ni lóhùn mọ́, ó kú, okàn rẹ̀ ti lọ, ara rẹ̀ ti tutù, ikú dé. Báyìí ni a sọ ọkan pàtàkì nù nínú wa, a sì gbẹ́ ihò, a sin ín síi, a sì sọkún a káànú rẹ̀ bí ó ti yẹ. Ìnàkí-gorí-ìtẹ́ mú aṣọ dúdú kékeré, ó sánan mọ́ aṣọ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àmì ọ̀fọ̀ Gọ̀ǹgọ̀ṣútàkìtì tii ṣe àbúrò rẹ̀. ÀLÀBÁPÀDÉ ẸLẸ́GBÁRÁ L ẹ́yìn èyí, a kọjú sí ọ̀nà Igbó Elégbèje à ń lọ. A kò rí nǹkan abàmì kan tí ó ṣe pàtàkì fún ọjọ́ díẹ̀, ó tó bí ojọ́ mẹ́ta tí a tì sin Gọ̀ǹgọ̀ṣútàkìtì kí ó tó di pé nǹkan mìíràn tún dé bá ni, báyìí ni: `Bí a ti dé ibi kan báyìí tí ó ttẹ́jú díẹ̀ tí a dúró tí a jẹun tán ni a déédéé gbọ́ ariwo ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọdé ní apá ọ̀nà ibì tí à ń lọ tí wọ́n ń ké bọ̀ lápá ọ̀dọ̀ wa. Àyà mi já púpọ̀ nítorí igbe yìí nítorí igbe yìí nítorí mò ń bẹ̀rù kí ó má baà jẹ́ iwin burúkú tí òkìkí rẹ̀ ti kàn jákè jádò óde aayé tí à ń pè ní Ẹlẹ́gbára. Iwin burúkú ni, bí o bọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ tí à ń pè ni ni ọmọ ẹlẹ́gbára ni ó máa ń ṣáájú tí wọ́n má ń kéde bíbọ̀ rẹ̀ fún gbogbo ohun alaàyé. Bàbá mi tì ròyìn iwin náà fún mi rí, ìbejì ni pẹ̀lú èṣù, awọn méjéèjì si ni àwọn ọmọ aráyé ń bọ ní ìkoríta. Nítorí náà, ìgbà tí mo déédéé gbọ́ ariwo láàrin aginju yìí, ẹ̀rù bà mi gidigidi. Lóòótọ́ náà, bí mo ti rò ó si ló bọ́ sí. Nígbà tí ó ṣe tí ariwo náà túbọ̀ ń súnmọ́ wa ni a bẹ̀rẹ̀ si i gbọ́ ohun tí wọn ń wí. Won ń ké báyìí, ‘A kì í wó o, ẹ yàgò fùn un, ẹ yàgò fún un. Máa rọra, máa wolẹ̀, kíyèsí kòtò, kíyèsí pàǹtí, kíyèsí gegele òkúta. E:-:-:-e!, E:-:-:-e, Ẹlẹ́gbára ń bọ̀ lọ́nà o, ọ̀gọ lẹ́yìn aṣiwèrè, kùmọ̀ lẹ́yìn aláìgbọràn, ìjàngbọ̀n lẹ́yìn olórí kunkun, E:-:-:-e!, E:-:-:-e! Ìbosí o, ìbòsí o, Ẹlẹ́gbára ń bọ̀ lọ́nà o- a kì í wò ó, ẹni wòó á kú, ẹni kò ó ìjàngbọ̀n lọ́nà, ẹni ríi, rí ìbànújẹ́ ọ̀ṣán gangan, a kìí wò ó! A kì í wò ó! A kì í wò ó:-:-:-:-:-abbl. Báyìí ni a bẹ̀rẹ̀ síí gbọ́ igbe náà tí o ń túbọ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ wa. Wéré a yára di ẹru wa, bí a sì ti ń dìí tán náà ni a wo iwájú tí àwọn ọmọ Ẹlẹ́gbára yọ sí wa. Kò sí ẹni tí ẹ̀rù kò bà nínú wa nígbà tí wọ́n yọ, àfi bí a bá máa púrọ́. Ìgnà tí wọ́n sì ti yọ ni a ti tú sí igbo tí olúkúlùkù sá pamọ́ bẹ̀rẹ̀bẹ̀rẹ̀, kẹkẹ kò gbọdọ gbin. Ẹlòmíràn sá gun orí igi, ọmọde kò lè rí ẹ̀rù kí ẹ̀rù má bà á - Ẹlẹ́gbára kúrò ni nǹkan yẹpẹrẹ. Orí àpáta ńlá kan báyìí ni mo gùn lọ ni tèmi. Láti ibẹ̀, mo lè rí ìsàlẹ̀ kedere, àwọn igi ìtàkùn tí ó hù sí orí àpáta náà sì dáàbòbò mi, mo sá pamọ́ sí ẹ̀yìn wọn, àwọn dúró bí awọ́n fún ojú mi. Ibẹ̀ ni mo wà tí mo rí àwọn ọmọ Ẹlẹ́gbára tí wọ́n ń kọjá lọ, mo rí wọn dáadáa. Wọ́n tó àádọ́ta wọn kò sì pa ju ẹsẹ̀ bàtà mẹta mẹ́ta lọ, wọ́n fi ẹfun òun osùn sá ojú, wọ́n so ìyẹ́ mọ́ orí, wọ́n dudu mọ́namọ̀na. Wọn kò wọ ẹ̀wù bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wọ ṣòkòtò, ṣùgbọ́n wọ́n sán yẹ̀rì mọ ìdí, ẹyọ owó sì bo yẹ̀rì náà pátápátá. Wọ́n to ìlẹ̀kẹ́ láti orúnkún lọ sí ìsàlẹ̀, ìgbà tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n tò ó dé ọrùn ẹsẹ̀, wọ́n dáwọ́ rẹ̀ dúró, wọ́n sì wá mú ẹ̀gbà ide, wọ́n tò ó yí ọrùn ẹsẹ̀ po, wọ́n ge idẹ pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ wọ́n so ó mọ́ ẹ̀gbà wọ̀n-ọnnì, eléyìí nì sì ń dún woro-woro bí wọ́n ti ń sáré kọjá lọ. Ojú mi gbangba báyìí ni wọ́n ṣe ń kọjá,mo sì dúró mo n wo ìgbà tí Ẹlẹ́gbára pàápàá máa tẹ̀lé wọn. Mo dúró títí bí ẹni pé kí Ẹlẹ́gbára pàápàá kọjá, kò kọjá, àkókò gan-an tí mo sì bẹ̀rẹ̀ síí ronú pé kò níí wá mọ ǹ jẹ́ ki n súfèé pe àwọn yò’kù mi ni mo déédéé ri ti ilẹ̀ ń mi tìtì tí ogunlọ́pọ̀ àwọn ẹranko ń sá kiri, àwọn ẹyẹ pàápàá kò fi ara balẹ̀ mọ́, wọn ń kígbe léra léra, àwọn ejo ń sáré gun igi wọ́n tún ń wọ lulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni igbe àwọn ọ̀kẹ́ẹ́rẹ́ gba agbegbe kankan. Ìgbà tí mo tún bẹ̀rẹ̀ si i rí àmì wọ̀nyí, mo túbọ̀ mú ara dúró, kí n ma ba wá lọ̀ bọ́ sí ọwọ́ Ẹlẹ́gbára. Nígbà tí ó ṣe, mo ń Ẹlẹ́gbára tí ó yọ lọ́kàn-án-kán, ó ba ni lẹ́rù gidigidi. Ó gbé àpò ńlá kan kọ́ èjìká, ó sì kó kùmọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́. Irun orí rẹ̀ gun, ó dúdú, ó sì kun fún ípàǹtí, òṣù kan tí ó wà láàrin orí náà gùn, o sì ń kàn án ní ìdí bí o ti ń rìn lọ. Mo rí ogunlọgọ̀ àdó àti àákàrè igba tí ó tó mọ́ra láti ìbàdí títí o fi dé ẹsẹ̀ koko, mo sì rí eyín rẹ̀ tí ó dàbí eyín kìnìhún, bẹ́ẹ̀ ni iwin burúkú yìí ń wo ọ̀tún tí o ń wo òsì tí ó ń wá wa kiri, nítorí ó ti gbóòórùn wa. Nígbà tí ó ṣe ni mo rí Ayédèrú-ẹ̀dá tí ó sá jáde ni abẹ́ ìtàkùn tí ó sá pamọ́ sí, nítorí Ẹlẹ́gbára ju kùmọ̀ sí ibẹ̀, Ayédèrú-ẹ̀dá wá ṣebí ó rí òun ni.Ìgbá tí ó sá jáde yìí ni Ẹlẹ́gbára pàápàá tó ri i, wéré ó sì ti dì í mú, bí ó sì ti fẹ́ pa á, Ayédèrú-ẹ̀dá kígba ó nu, ‘Jọ̀wọ́ ṣe mi jẹ́jẹ́ ki n bà fi ibi tí àwọn yòókù wà hàn ọ, nítorí a pọ̀ jù báyìí lọ.’ Ìgbà tí ó wí báyìí tán, iwin náà kò pa á, ó ni kí ó maa fi ibi tí a sá pamọ́ sí han òun, wéré Ayédèrú-ẹ̀dá tọ́ka sí mi ní ibi tí mo lóṣòó sí tí mo fi àwọn ewé bojú lórí àpáta. Nígbà tí iwin náà rí mi, ó yara ju Ayédèrú-ẹ̀dá sínú àpò ó ń sáré bọ̀ lọ́dọ̀ mi. Bí ó ti ń bọ̀ ni mmò ń ronú ohun tí mo máa ṣe. Àwọn ìtàkùn àti igbó dúdú kan báyìí wà ní ìsàlẹ̀ àpáta ní apá òdìkejì ibi tí òun ń bá gun òkè bọ̀, mo sì ti rọra yọ́ sọ̀kalẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti sòfófó mi fún un mo rá wọ abẹ́ ìtàkùn náà mo fi ara pamọ́ bẹ́rẹ́bẹ́rẹ́. Óun ń gun òkè bọ̀ lórí àpáta, ibi tí o sì ti ń fi iwọra sáré bọ̀ kò mọ ìgbà tí mo fi rọra sọ̀ kalẹ̀ sí òsì kejì. Ṣùgbọ́n ìgbà tí ó dé orí àpáta tí kò tún rí mi mọ́, o fura pé abẹ́ ìtàkùn náà ni mo wà, ó ju kùmọ̀ rẹ̀ síbẹ̀, èyí tí o kọ́ jù bá mi ní ìpàkọ́ ṣùgbọ́n n kò mira. Ó ju ẹ̀kejì èyí bá mi ni iwájú n kò sọ̀rọ̀. Ẹ̀kẹta tí ó jjù bá mi ni góńgó imú mi, mo rọra fi ọwọ́ ra inú mo dákẹ́ jẹ́jẹ́. Ẹlẹ́gbára náà bá dáwó dúró o ń wo gbogbo àgbègbè. Ìgbà tí ó pé ṣa, ọkàn rẹ̀ sọ fún un pé ìbẹ̀ ni mo níláti wà, nítorí kò rí mi ki ń jáde lágbègbè ibẹ̀, ó bá mu àdó kan jáde, nígbà tí ó sọ àdó sí abẹ́ ìtí, àdó gbiná, iná ń jò bọ̀ lọ́dọ̀ mi mo bá fò jáde tí Ẹlẹ́gbára náà gbá tẹ̀lé mi, èmi tí mò ń sáré ikú mo ń lọ nínú igbó gbururururururu. Ibi tí o ti ń lé mi lọ àpò já láti èjìká rẹ̀ sílẹ̀, Ayédèrú-ẹ̀dá sá jáde. Ìgbà tí iwin náà rí èyí, ó yípadà ó bẹ̀rẹ̀ síí le Ayédèré-ẹ̀dá lọ èmi náà tún ń sá gba ọ̀nà tèmi lọ. Nígbà tí ó ṣe, ó rántí àpò rẹ̀ tí ó bọ́, o fi àwa méjéèjì sílẹ̀ ó wá àpò rẹ̀ lọ. Mo gun orí igi kan lọ lẹ́yìn ìgba ti n kò gbúrò rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n kò pẹ́ púpọ̀ náà tí mo ń wo Ẹlẹ́gbára tí o ń wò ọ̀hún tí o ń wo ìhín tí o ń pòṣé tí ó n wá wa kiri, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ó ń sọ báyìí! A, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ wọ́n lọ. Bẹ́ẹ̀ ni iwin náà bẹ̀rẹ̀ sí í wí tí ó ń wọ igbó kiri tí o ń kígbe pe orí ara rẹ̀, o n wo ìhìn, o ń wo ọ̀hún o ń wo òkè o ń wo odò, o ń wá wa kiri, olúkúlùkù pa lọ́lọ́, ẹnìkan kò gbọdọ gbin, ẹni wúkọ́ dáràn, ẹni yísẹ̀ padà gbé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ pínkín, ta ni baba tí ó b�� olúwarẹ̀! Àwọn Ẹranko pàápàá kò gbádùn, igbó dákẹ́ bí ẹni pé ọ̀fọ̀ ṣẹ ènìyàn. Ó ṣẹ ẹranko, emi náà rọra jókòó mo ká gúlútú lórí igi. Nígbà tí o ṣe o ń bọ̀ lápá ọ̀dọ̀ mi, nígbà tí o sì de ibẹ̀, ó wo ìsàlẹ̀, o wo abẹ́ ìtàkùn, ó wo òkè, ṣùgbọ́n kò rí mi lábẹ́ ewé o sì kọja sí apá ẹ̀yìn mi, o lọ. Èmi ìbá mọ̀ ki ń yára sọ̀ kalẹ̀ kí n wa ibòmíràn sá sí! Nígbà tí o lọ síwájú díẹ̀ ó tún padà sẹ́yìn nígbà tí o sì ń bọ̀ lẹ́ẹ̀kejì nì, tí ó tún gbé ojú sókè, A! Ó rí mi, alákọrí ri mi, ìjàngbọ̀n tún bẹ̀rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ si mi igi mọ́ mi ní ìdí ki n bà já tilẹ̀, mo tilẹ̀ kọ́ rò pé kò rí mi ni àti pé ó kàn n mi igi lásán ni, ìgbà tí mo sì rọra dákẹ́ ti n kò sọ̀rọ̀ ó dáhùn ó ni, wo ilẹ̀ kí o wo ọ̀run, mo ti rí ọ, ọwọ́ ba ìwọ ní tìrẹ ná...abbl Nígbà tí ó ti sọ báyìí, mo mọ̀ pé ó rí mi, mo rọra dide láàrin ẹka igi tí mo fò tagbáratagbára mo balẹ̀ síwájú ibi ti iwin náà wà, wéré ó ti fò tì mí ṣùgbọ́n kí ó tó kàn mi lára, mo ti dide mo fi iré síi, èyin ọ̀rẹ́ mi nnǹkan dé, Ẹlẹ́gbára náà gbé eré dà sílẹ̀ o, ó ń sáré oúnjẹ, èmi ń sáré ikú, ọ̀r[sn di gburururururu! Mo gbọn ire bí ẹni gbọn òwú, iwin náà sì ń lé mi, a sáre títí a fi de ibi ihò títóbi kan báyìí, nígbà tí mo sì dé ibbẹ̀ mo kó sii, àṣé ihò kìnìhín ni, ìgbà tí kìnìhún sì rí mi tí mo ń sá bọ̀ ó ṣebí Ẹlẹ́gbára ni mi, dípò kí ó bá mi jà, ó sá jáde, ìgbà tí ó máa jáde, ó pàdé Ẹlẹ́gbára, ó sebí ènìyàn ni, ó bá bẹ̀rẹ̀ ìjà pẹ̀lú Ẹlẹ́gbára, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìjà, ibi tí wọ́n ti ń jà, mo sá jáde. N kò sá jìnà jù bẹ́l lọ tí iwin náà fi fa kìnìhún ya tí ó tún n lé mi lọ. Èmi náà sì múra mo fi iré si í. Nígbà tí ó ṣe o lé mi dé ibi odo ńlá jíjìn kan, ibẹ̀ lo sì ti ní ìrètí àti mú mi. Nígbà tí mo dé etí odo yìí, dípò ki ń dúró, ṣe ni mo bẹ́ si i, tí mo mòòkùn lọ, ìgbà tí mo sì maa jáde aarin omi ni mo jáde sí mo bá fi ìwẹ̀ si i, mo wẹ̀ já sí odì kejì odò. Ṣùgbọ́n iwin náà kò le wẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí o rí i pé mo wẹ̀ dé òdì kejì, tí emi wà ní apá ọ̀hún tí òun wà ni apa ìhín, ó pòṣé, ó ta ìkà sí mi, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Ibi ti mo ti ń sími yìí ni mo ti déédéé rí obìnrin arẹwà kan tí ó yọ sí mi. Ó lẹ́wà gan-an ni, ó wọ aṣọ darádára, ara rẹ̀ tutu nini, ó mọ́ tónítóní, ara rẹ̀ ń dán bí ara ọmọ kékeré, eyín rẹ̀ funfun bí asọ àlà, ojú rẹ̀ gún bí ojú òṣùpá, ẹyínlójú rẹ̀ mọ́lẹ̀ kedere, ẹ̀yà ara rẹ̀ wà ní ìwọ̀ntun-wọ̀nsì, wọn bá ara ṣe dọ́gbadọ́gba, ó ró aṣọ, ó wé gèlè, ó mú ìbòrùn lọ́wọ́, o fi yẹrí sí etí, o fi òrùka sí ọwọ́ ó sì wọ sálúbàtàtà idẹ. Ènìyàn dúdú ni, ó fi dúdú wu ni. Nígbà tí obìnrin náà rí mi, ó wá sí ọ̀dọ̀ mi, ó rẹ́rìn-ín o sì bẹ̀rẹ̀ síí wádìí bí mo ti n rìn tí òun fi rí mi o wá sí ọ̀dọ̀ mi nini tí mo wà, mo sàlàyé fún un dáadáa, ṣùgbọ́n bí o ti ń sọ̀rọ̀ ni o ń rẹrìn-ín músẹ́ sí mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀nọnnì sì ṣe mi lóòre lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ayé ti ṣu mi ni àkókò tí a ń wí yìí, ọkàn mi sì tilẹ̀ ti ń kábàámọ̀ pé kí ni ṣe tí n kò jẹ́ kí Ẹlẹ́gbára kúkú pa mi jẹ. Nígbà tí obìnrin náà jókòó díẹ̀, ó díde, ó lọ bu omi tútú fún mi mu, omi náà tutu ju omi etí odó tí mo wà ni ìgbà mẹ́wàá, nígbà tí o sì wòye pé àárẹ̀ ti mu mi jù, ó lọ mú òògùn wá, oogun náà nínú ìgò kan báyìí, ìgbá tí ó sì bù díẹ̀ nínú òògùn náà sí inú galafi kan fún mi tí mo mu u, ṣe ni ara mi le gaú, ọkàn mi sọ jí. Ìgbà yìí ni mo lè sọ̀rọ̀ sí obìnrin náà dáadáa, mo sì bèèrè bí o ti ṣe dé ibẹ̀. O sọ fún mi pé ènìyàn ni ìyá òun ṣùgbọ́n ẹbọra lo bí òun fún àti pé ẹbọra náà ni ọba àgbègbè ibi tí a wà àti pé ààfin bàbá òun kò jìnà sí etí omi tí òun ti rí mi, ó rọ̀ mi pé ki ń wá lọ mọ ilé òun kí n kí bàbá òun ṣùgbọ́n mo kọ̀ mo wí fun un pé mo sa n fẹ́ kí ọkan mi túbọ̀ balẹ̀ díẹ̀ sii ni ni n wẹ̀ padà sí òdí kejì odò ki n wá àwọn tí a jọ ń bọ̀ lọ. Lẹ́yìn èyí, obìnrin náà bèèrè bí mo ti ní ìyàwó mo sì wí fún un pé n kòì tìí ní, àti pé nǹkan bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ tíì sí lọ́kàn mi, ohun tí ó lékè ẹ̀mí mi kò ju pe ki ń ṣe asáájú àwọn ènìyàn mi de Òkè Ìrònú ti ń bẹ nínú Igbó Elẹ́gbẹ́je. Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀, ó rẹ́rìn-ín, ọkan mi sì bẹ̀rẹ̀ si rò pé ó ń fẹ́ ki n fẹ́ òun ni. Kìí ṣe pé ó fi ẹnu rẹ̀ sọ, èmi rò bẹ́ẹ̀ ni. Nítorí mo ti mọ̀ pé ìba díẹ̀ nínú obìnrin ni wọn lò fi ẹnu ara wọn sọ fún ọkùnrin kí ó fẹ́ àwọn, bí ìfẹ́ tilẹ̀ ń pa wọn bí ọtí, tí o tì wọ́n ká bí ẹni tí òrìṣà gùn, àti la ẹnu sọ̀rọ̀ náà jáde a máa jẹ́ ìṣòro. Ṣùgbọ́n obìnrin náà ṣe aájò mi púpọ̀ ọ̀ran rẹ̀ ló sì jẹ́ ki n mọ̀ pé ìfẹ́ a máa fa ìfẹ́ yọ, nítorí sáájú àkókò náà, n kìí fẹ́ràn obìnrin rara ó sì dàbí ẹni pé ìṣẹ̀dá mi ni ki n máa kórira wọn ṣùgbọ́n nígbà tí mo máa fi eléyìí sílẹ̀ omi fẹ́rẹ̀ bọ́ lójú mi bẹ́ẹ̀ ni n kò sì tilẹ̀ ní ọkàn àti fẹ́ ẹ. Oun náà lo ṣe ọ̀nà tí mo fi yọ lọ́wọ́ Ẹlẹ́gbára, níbi tí a ti ń sọ̀rọ̀, ó bèèrè ohun tí mo rò pé òun lè fi ràn mi lọ́wọ́ mo sì ròyìn ìyọnu tí mo ti bá pàdé fun un. Lẹ́yìn èyí, ó pe àbúrò rẹ ọkùnrin, nígbà tí ó dé, o wí fún un pé kí o lọ gbé ọkọ̀ wá kí ó tù mí kọjá sí apá kejì odo, wéré wọ́n ti mu ọkọ̀ dé, àti èmi àti oun sì rékojá sí òdì kejìo lápá ibi tí mo wà. Kí a tó bọ sí inú ọkọ̀ ó ti béèrè nípa Fìlásayépọ̀ nítorí ó wí pé ẹgbọ́n òun ni, bàbá rẹ̀ jẹ́ àbúrò bàbá òun àwọn méjéèjì wá jẹ́ àbúrò olókun tíí ṣe alákòóso omi. Ó ní bàbá òun tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ayédùbúlẹ̀ ni ẹni t;i wọ́n bí bàbá Fìláswayépọ̀ ń gbé kiri. Ó wí fún mi pé ó yẹ kí a wa Filásayépọ̀ rí, nítorí bí a bá le ríi, iwin tíí ṣe alákòóso fìlà rẹ̀ yóò kó wa yọ. Nígbà tí a gúnlẹ̀ sí òdì kejì tán, ó wí pé kí àbúrò òun tó jẹ́ iwin wá Fìlásayépọ̀ wá nní ibikíbi tí ó bá ti lè rii. Wéré tí ó wí báyìí, ṣe ni àbúrò rẹ̀ rá mọ́ wa lójú, nígbà tí o sì fi máa tó ìsẹ́jú mẹ́ta ṣe ni mo rí i tí o ń fò bọ̀ lófurufú tí ó gbé fìlàsayépọ̀ lé èjìká, tí ó gbé e kalẹ̀ lọdọ wa. Ìgbà tí iwin yìí rí fìlásayépọ̀ wọ̀n yọ̀ mọ́ ara wọn, wọ́n sì kí ara wọn dáadáa. Lẹ́yìn náà ó ni ki filásayépọ̀ pe iwin inú fila rẹ̀ fun òun, onítọ̀ún sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí iwin náà dé, kò ga púpọ̀, o sì sanra o ni iké ńlá kan lẹ́yìn. Òun ati obìnrin yìí sọ̀rọ̀ sí ara wọn ní èdè tì n kò gbọ rí, lẹ́yìn náà ni iwin tii ṣe alákòóso filà yìí bẹ̀rẹ̀, tí o ní ki n jókòó lé òun lẹ́yìn, nígbà tí mo sì ṣe bẹ́ẹ̀, wéré ni mo bá ara mi ni ofuurfú tí o ń fò lọ pẹ̀lú mi. Àyà mi kọ́ já ṣùgbọ́n ó ni ki n dì mọ́ òun lẹ́yìnn dáadáa kì n má ba à já lulẹ̀ mo rọra dọ̀bálẹ̀ lé e lẹ́yìn mo di iké ẹ̀yìn rẹ̀ mú dáadáa. Iwin náà ni irun lára bi ti ẹranko gan-an ni, irun wọ̀nyí ni mo si di mọ́ pẹ̀lú iké ẹ̀yìn rẹ̀ tí kò jẹ́ kí n já ṣubú. Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀ ó gbé mi sọ̀kalẹ̀ sí ojú ọ̀nà Igbó Elégbèje, ó sì wí fún mi pé a ti kúró ní àgbègbè ibi tí Ẹlẹ́gbára máa ń dé, ṣùgbọ́n ó wí fún mi ki n má kúrò nibi tí òun gbé mi s’’i nítorí òun ń lọ máa gbé àwọn yòókù lọ́kọ́ọ̀kan wá. Lóòótọ́ náà, iwin inú fìlà yìí bẹ̀rẹ̀ sii wá àwọn ẹnìkejì mi yòókù kiri, o sì ń gbée wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi lọ́kọ́ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ ló ṣe títí ó fi gbé gbogbo wa tán. Ṣùgbọ́n nígbà tí a wo ààrin wa, a kò rí ọkùnrin kan báyìí tí o ń jẹ́ ìgbí-ènìyàn, ó jẹ́ ẹni tí kìí fi ìkánjú ṣe nǹkan kan rárá, bí ó bá ń rìn pàápàá náà báyìí, tẹ̀ǹkì-tẹ̀ǹkì ló máa ń rìn kiri ìgbà tí iwin náà gbé ojúayédùn dé nítorí òun ló gbé kẹ́yìn pátápátá, ó wi fún ni pé kò sí ẹnìkan lọ́hùn-un mọ́. A ba wí fún olójúmájèlé kí ó ba ni fi eyín erin rẹ̀ wo inú igbó náà bóyá ó lè jẹ́ rí i. Ìgbà tí ó ṣe bẹ́ẹ̀, kò ríi, ṣùgbọ́n ó wí fún ni pe òun ri Ẹlẹ́gbára pàápàá, o ń jẹ òkú ènìyàn kan lọ́wọ́ àti pé òkú ènìyàn náà jọ òku Ìgnín-ènìyàn, nígbà tí àwa náà wò ó, òun ni. Ẹlẹ́gbára ti fa ọkùnrin náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, báyìí ni a sì ń wò ó tí o ń fọ́n egungun agbárí Ìgbín-ènìyàn bí ẹni fọ́n fèrè. Nínú gbogbo wa, kò sí ẹni tí kò fi ara pa àfi Ìbẹ̀ǹbẹ́-Olókùnrùn. Ó jẹ́ ẹni tí ó sanra púpọ̀ ó sì yà mi lẹ́nu bí òun ti ṣe lọ ni orí ire bẹ́ẹ̀, ìgbà tí Ẹlẹ́gbára ti tú wa ká tí òun sì ti rọra fi ara pamọ́ sínú igbó ṣúúrú kan, Ẹlẹ́gbára kò rii títí gbogbo wa fi ń sá gun òkè sá gun gègéle. A dúró, a simi díẹ̀, olúkúlùklù ròyìn ohun tí òun bá pàdé ni ibi tí òun ti ń sá kiri, a dúpẹ́ lọ́wọ́ iwin inú Fìlàsayépọ̀ kí ó tó tún di pé o padà wọ inú fìlà ọ̀rẹ́ wa lọ. Lẹ́yìn èyí, a kọjú sí ọ̀nà wa. A rin títí ilẹ̀ ọjọ́ kéjì fi ṣú láàrí ìyọnu kan àfi ti Ìbẹ̀ǹbẹ́ olókùnrùn tí o ń kígbe ebi. Ìgbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kẹta mọ hàì ni a já sí igbó àwọn ẹran kan báyìí tí wọn kò sì sá fún ni títí a fi kànj wọ́n lára. Wọ́n tóbi púpọ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n tóbi tó màlúù dáadáa, a pa nínú wọn, gbogbo wa jẹ, Ìbẹ̀ǹbẹ́-olókùnrùn sì pa púpọ̀ jẹ nínú wọn. ÌLÚ ÀWỌN ÈDÌDÀRẸ́ NÍ IBI TÍ ÒMÙGỌ́DIMÉJÌ Ti Ń ṢE ỌBA WỌN N ígbà tí a kúrò ní ibi tí àwọn ẹranko wọ̀nyí wà tí a túbọ̀ rìn díẹ̀ síwájú si a rí ọ̀nà kékeré kan báyìí tí ó yà bá apá òsì lọ. Wọ́n kọ àkọlé kan sí ìyànà náà, nǹkan tí wọ́n sì kọ ni èyí: ‘Ìlú àwọn Èdìdàrẹ́ níbi tí òmùgọ́diméjì ti ń ṣe ọba wọn.’ Àkọlé yìí yà wá lẹ́nu a sì yà sí ọ̀nà náà kí a ba lọ wò bí ibẹ̀ ti rí. nígbà tí a rìn sí iwájú díẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ sii wo ìlú náà ní ọ̀kánkán ṣùgbọ́n ọ̀nà tí à ń tọ̀ lọ túbọ̀ ń di kékeré sii àfi bí ẹni pé ènìyàn kò ń gbá ìlú náà ni, nígbà tí ó sa pẹ́ sá, a yọ sí ìlú yìí. Èmi ni mo wí fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, lọ́jọ̀ tí mo ti dé inú ayé n kò rí ìlú tí ó jẹ́ ìlú eléèérí bi ìlú yìí rí. Ìgbà tí a dé aarin ọjà, gbogbo ìbẹ̀ ń rùn ni, kò dàbí ẹni pé ẹnikẹ́ni gba aarin ọjà náà rí. gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn, arúgbó lo ń ta ọjà, òun ló gbọ́dọ̀ kiri, gbogbo àwọn tí a sì bá nínú ọjà náà kò ju àádọ́ta lọ, gbogbo wọn ni wọ́n sì ti fi gbogbo orí hu ewú pátápátá, wọn ìbá sì tilẹ̀ pọ̀ jù bẹ́l lọ bí ko ṣe pé wọn kò ń pẹ́ kú ní ìlú náà. Orí ìpàǹtí ni wọn gbé gbogbo ọjà títà lé. Ìhòòhò ni púpọ̀ nínú àwọn tí a rí wà, tó bẹ́ẹ̀ tí ó jẹ pé bí wọn ba ń kọjá, eeri n gbọ̀n silẹ̀ ni, ọdún mẹ́ta mẹ́ta ni wọn to ń wẹ̀, èérí ara wọ́n pọ̀. Mo rò pé eléyìí náà ló mu kí kúrúnà kúkú pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ní ìlú náà, ṣùgbọ́n èyí tí ó buru ju kúrúnà ni egbò ẹsẹ̀ Olúkúlùkù tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí àṣà fún àwọn gbájumọ̀. Ewé kékeré kò tó láti fi bò wọn, omi egbò ẹsẹ̀ awọn ara ìlú náà a sì maa kán sílẹ̀ bí wọ́n bá ti n rìn lọ. Iná orí àti iná aṣọ pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ idun ti ṣe ọ̀nà sí ara wọn. Àwọn kòkòrò wọ̀n-ọnnì rí i pé ibẹ̀ dára gẹ́gẹ́ bí ilé fún àwọn. Kò sí ibi ti jìgá ko lè wọ lara àwọn Èdìdàrẹ́, jìgá kọ́ pẹ̀tẹ́ è si sí wọn ni àtẹ́lẹsẹ̀, o kọ ilé ilẹ̀ sí wọn ni ìbàdi, ṣùgbọ́n ori ni aafin àwọn ina wa. Èékán ọwọ́ wọn mu bí àdá, Ìgbà tí wọ́n bá sì ń họ ara, a máa dún kùràkùrà bí ìgbà tí àgbẹ̀ ba ń fi ọkọ́ ro oko. Omi tí wọn ń mu ni ìlú yìí burú gidigidi, nítorí etí odò tí wọ́n ti ń pọn ọ̀n ni wọn ń, ṣe ìgbọ̀n sẹ̀ sí bẹ́ẹ̀ ni odò náà kò ju kékeré lọ. Nígbà ti a ti dé aarin ọjà wọn tí a wo ìwà wọn tí ó burú bi mo ti ròyìn yìí ni a ti pinnu pé ó yẹ ki á pa àgọ́ sí etí ibẹ̀ kí a wò wọ́n fún ọjọ́ mélòó kan. Àgọ́ tí a pa tó ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún sí ìlú yìí, nítorí etí ibẹ̀ kò wu wa láti pa àgọ́ sí. Èyí tí ó burú púpọ̀ ní ìlú yìí ni ìwà wọn sí ara wọn. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn Èdìdàrẹ́, ọmọdé ló ni ayé, àwọn àgbàlagbà kò jámọ́ nǹkan kan. Bí ilẹ̀ bá mọ, bàbá á dọ̀bálẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀ káàkiri ilé, ìyá a tún kúnlẹ̀ fún wọn. Bí ọmọdé bá máa ránṣẹ́, a rán àgbàlagbà ní iṣẹ́, bí ọmọdé àti àgbàlagbà bá jẹun tán, àgbà ni ń fọ àwọ. Àwọn obìnrin ní n ṣíṣẹ́ líle àfi ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni àwọn ọkùnrin ń ràn wọ́n lọ́wọ́ ṣùgbọ́n ìgbà tí àwọn obìnrin bá dé oko tán wọn á wá iṣu lé ọkọ wọn lórí, a rù ú bọ̀ láti oko. Bí ọmọdé bá ti gbé nǹkan tí ó wúwo díẹ̀ lọ́wọ́, àwọn àgbà nílatí sáré gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Bí ọmọdé àti àgbà bá lọ sí oko ìbáà ṣe ọkùnrin ìbáà ṣe obìnrin, àgbà ni ó nílati ru erù bọ̀. Ìgbà tí wọ́n bá sì wà ní oko, àgbà ni ó nílati dá iná kí ó ṣe oúnjẹ. Wọ́n kì í sìnkú ní ìlú náà. Bí ẹnìkan bá kíi, oúnjẹ dé, nítorí jíjẹ ni wọn ń jẹ òkú ara wọn ṣùgbọ́n wọn ko kẹ́ déédéé pa ara wọn jẹ. Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ bá kú pọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo wọn á rọra gbé òkú wwọn sí àgbàlá wọ́n a máa jẹ ẹ́ díẹ̀díẹ̀. Bí o sì tilẹ̀ jẹ́ pé wọn má a ń sun ẹran ènìyàn kí wọ́n tó jẹ ẹ́, síbẹ̀ wọn kò mọ ọ̀nà àti yan òkú tí ó bá kú tí kò ní fi bàjẹ́, ìgbà tí wọ́n bá sì gbé e sí ẹ̀yìn kùnlé tó bí ọjọ́ mẹ́ta èyí nì a bẹ̀rẹ̀ sí í rùn ṣùgbọ́n àkókò náà ni wọn má a ń sáré pe ọ̀rẹ́ wọn kí ó wá jẹ àṣè ní ilé wọn, wọ́n á ni àwọn n ṣe sàráà kí ẹ̀mí àwọn bà gbó. Bí wọn ti ń kọ ilé wọn kò dára rárá, nítorí kì í sí ẹyọ ferese kan ní ilé wọn, gbogbo ibẹ̀ á ṣókùnkùn dudu, atẹ́gùn kì í síí rí àyè dé ibẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Koríko ni wọ́n fi bo ilé wọn ìgbà tí òjò bá sì rọ̀, ìgbà púpọ̀ ni ilé ń jò tí gbogbo ilẹ̀ á tùtù nini, ewéko ni wọ́n n tẹ́ sílẹ̀ sùn, wọ́n á fi okúta ṣe ìrọ̀rí, wọn kò ni ẹní kan ṣoṣo. Bí mo ti wí lẹ́ẹ̀kan, aṣọ kò wọ́pọ̀ ní ìlú náà, nínú agbo ilé ìbẹ̀, púpọ̀ ló jẹ́ pé aṣọ kan ṣoṣo ni ó wà fún gbogbo wọn, wọ́n a si ṣe èetò bí awọn ó ti ṣe lò ó. Ẹni kọ̀ọ̀kan níí sábàá máa lò ó lójoójúmọ́, èyí nì ni pé bí àwọn ọmọ ilé náà bá jẹ́ ọgbọ̀n, oṣooṣù ni aṣọ náà ó tó máa kan ẹni kọ̀ọ̀kan, nítorí náà ní àkókò òtútù, ewé ni wọ́n ń lò jù bí aṣọ. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yín náà ti mọ̀, ìlú tí ó kún fún èérí bí irú èyí tí mo ń sọ yìí kò lè ṣai ní àwọn aláì sàn nínú. Kò sí ibi náà ní ode ayé yìí tí aisan pọ̀ to tayọ tí ilú Edidarẹ nibi tí omugodimeji ti ń ṣe ọba wọn. Kí a filẹ̀ mú ti èérí kúrò, ki ni kí a ti pe ti ilé wọn tí kò ní fèrèsé tàbí ilẹ̀ ilé tí ó tùtù nini, kí ló lè mú àìsàn wá tí ó kọja irú èyí! Bí ìtàn ibẹ̀ ti lọ, ìlú náà ni o tóbi jù ni òde ayé ni ayé àtijọ́, odidi ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi ń rìn láti apá kan dé apá kejì ṣùgbọ́n nǹkan tí o sọ wọ́n dì bí wọn ti wa yìí ni ìrẹ́pọ̀ tí kò sí láàrin wọn. Wọ́n jẹ́ ẹ̀dá tí ó mọ ti ara rẹ̀ nìkan tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò sí irú wọn ṣáájú wọn tí kò sì lè sí irú wọn lẹ́yìn wọn. Wọ́n kún fún owú jíjẹ tó bẹ́ẹ̀ ti ó jẹ́ pé bàbá kò jẹ́ fi nǹkan kan ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìyá kò ni jẹ́ kí ọmọbìnrin rẹ̀ tilẹ̀ wò bí òun ti ń ṣe ọbẹ̀. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹníkan bá mọ ẹni kejì kò ní mọ̀ ọ́, bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ ọgbọ́n wọn ń parẹ́. Ó pẹ́ díẹ̀ tí a dé ìlú náà kí a to mọ ọba wọn. Ohun tí kò tilẹ̀ jẹ́ kí a lọ sí ilé ọba wọn kò ju èyí pe níwọ̀n ìgbà tí ìlú ti burú tó bí a ti báa yìí a kò ní èrò gíga kan nípa ọba ìbẹ̀ rárá, nítorí kò sí ọba pàtàkì kan tí ó lè fi oju ara rẹ̀ sílẹ̀ títí ìlú fi máa burú tó bí a ti báa nì. Ohun tí ó mú kí a tilẹ̀ pinnu àti lọ ilé ọba náà kò ju ti ilẹ̀ ẹ́ gbóná tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ;i jà ti ó sì jẹ́ pé o ń pa púpọ̀ nínú wọn. Nítorí èyí, a ránṣẹ́ lọ sọ fún ọba pé à ń bọ̀ wá ri i nípa ọ̀rọ̀ kan àti pé kí ó sọ ìgbà tí òun lè rí àyè rí wa. Nígbà tí oníṣẹ́ padà dé, ó wí fún wa pé ọba nì kí a wá sí aafin ní òwúrọ̀ ojọ́ kejì ní agogo mẹ́jọ̀-àbọ̀. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́ tí a jẹun a lọ sí ilé ọba. A dé ọ̀hún ní déédéé agogo mẹ́jọ-àbọ̀ gan-an, a rí ẹnìkan ti o ń bọ̀ láti aafin a sì wí fún un pé ọba wi fún wa kí á wá rí òun, ẹni náà bá padà wọ aafin lọ láti lọ sọ fún ọba, ṣùgbọ́n nígbà tí o máa padà dé, ó wí fún wa pé, ọba òmùgọ́diméjì ti lọ sí oko. Ní alẹ́ ọ̀jọ̀ náà, ni nǹkan bí agogo méje, a tún ránṣẹ́ lọ sí ààfin láti ba wa wò bí ọba bá ti dé, nígbà tí oníṣẹ́ wa padà ó wí fún wa wí pé ọba kòì tíì dé. Bí ilẹ̀ ti ń mọ ni ọjọ kejì, ti a ri i pé ó tó àkókò kí ọba tì maa rì àwọn ènìyàn rẹ̀, a tún ránṣẹ́ lọ sí ààfin. Ìgbà tí oníṣẹ́ pada dé o ní ọba wí pé ó rẹ òun lọ́jọ́ náà púpọ̀ nítorí ẹrù ti òun rù bọ̀ láti oko lọ́jọ́ tí a kọ́ wá a lọ́ pọ̀ ju èyí ti òun ti ń rù bọ̀ ri lọ, nǹkan agogo mẹ́sàn-án, èyí nì ní ọjọ́ kẹta tí a ti n wá a lọ sí aafin. Ní agogo mẹ́sàn-án gééré ni a dé ààfin ní ọjọ́ tí ó tún dá yìí, a tilẹ̀ kọ́ ṣebí a pẹ́ ni, ṣùgbọ́n nígbà tí a dé ọhún ni a mọ pe a dé sí àkókò gan-an. Bí a ti dé ọ̀hún ni a tún rán oníṣẹ́ kan wọ ààfin lọ. Ó pẹ́ díẹ̀ kí oníṣẹ́ náà tó padà, o wí fún ni pé ọba ti dé àti pe o n fẹ́ ri wa ní ọjọ́ kéjì ní déedée agogo mẹ́sàn-án àbọ̀. A dé ọ̀hùn bí ó ti wi lọ́jọ́ kèjì lóòótọ́, ṣùgbọ́n ọba ti lọ sí oko. Báyìí ni Òmùgọ́diméjì bẹ̀rẹ̀ síí ṣe títí ó fi di alẹ́ ọjọ́ kẹfà tí ó ránṣẹ́ pé kí a wá rí òun ní nǹkan bí agogo mẹ́wàá dípò agogo méjìlá tí o dá, ọjọ́ náà la sì kọ ríì. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé láti ọjọ́ tí a ti ń ránṣẹ́ yìí, onísẹ́ wa pàápàá kì í fi ojú rí ọba náà, ṣe ni wọn máa ń jíṣẹ́ fún un tí ẹni tí a bá ran náà máa ń ránṣẹ́ wọ ààfin lọ bí a si ṣe rí ọba yóò yà yín lẹnu. Aafin ọba Òmùgọ̀diméjì kò dara tó aba oko rara, ogiri ti wọ́n mọ yíí ká, ẹsẹ̀ méjì ni gíga rẹ̀. Lówùúrọ̀ ọjọ́ keje tí mò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, nígbà tí a dé aafin, a rí ẹnìkan tí ó jókòó lé orí ogiri tí o yí ààfin po. Ó sán ìbàǹtẹ́ mọ́ ìdí o sì pọ́n ìbàǹtẹ́ náà ni ìkólóbo. Ó tún dé fìlà gbọọrọ kan báyìí, kò wọ ṣòkòtò, kò wọ ẹ̀wù bẹ́ẹ̀ ni kò wọ bàtà rárá. Ọkùnrin yìí ni a ba ni orí ogiri. Inú wa dun tí a rii nítorí a n fẹ́ kí á tèlè rí ẹni tí yóò ba wa wọlé sọ fún ọba pé a ti dé. Gbogbo ìgbà tí a ti máa ń wá sẹ́yìn wọ̀n-ọnnì ni ìyà ma ń jẹ wa kí a to lè rí ẹni rán wọle, nítorí èyí inú wa dùn tí a tètè rí ẹnìkan ni ọjọ́ tí a n wí yìí. Wéré tí a ti ri ọkùnrin yìí la ti ṣo fún un pé a fẹ́ kí o ba ni wọlé lọ̀ sọ fún ọba pe a ti de. Nígbà tí a wí báyìí ọkùnrin náà béèrè nǹkan tí a fẹ́ rí ọba fún, a sì wí fún un pé a kòì tíì ṣeran láti sọ èyí nì fún ẹnikẹ́ni àti wí pé o di ìgbà tí a bá rí ọba kí a sọ fún un. Ìgbà tí o sì ń tẹnumọ́ ọ pé kí a sọ fún òun, inú bí wa a ṣebí o ń fẹ́ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọwọ wa kí ó tó wọlé lọ sọ ni. Ibi tí a ti jọ n sọ̀rọ̀ sì ara wa yìí ni ọkùnrin kan ti dé nígbà tí ó sì dé iwájú ẹni ti à ń bá sọ̀rọ̀ yìí, ó dọ̀bálẹ̀ ó sì kìí ‘Kábíyèsí aláṣẹ, èkejì òrìṣà’irú kíkí yìí jọ wa lójú a sì bẹ̀rẹ̀ sí í rò nínú ara wa pé bóyá ni ọkùnrin wọn ṣe máa ń ki ìránṣẹ́ ọba ni ìlú náà. Ṣùgbọ́n ibi tí a ti ń ronú bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin ti à ń bá sọ̀rọ̀ wí fún èyí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé pé àwa tí à ń lọ sí ìdálẹ̀ ni o rí níwájú òun àti pé a kò tilẹ̀ mọ òun pàápàá. Àkókò náà ni ẹni ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí sọ fún wa pé ọba ni à ń bá sọ̀rọ̀ àti pé òun ni ẹni tí ń jẹ́ Òmùgọ́diméjì tii ṣe ọba ìlú àwọn Èdìdàrẹ́. Bí ọkùnrin náà ti sọ báyìí tan ni a tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọba pé a kò mọ̀ pé òun ni. Lẹ́yìn èyí ni Òmùgọ̀diméjì bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ i sọ tí ó ni: Ẹ̀yin aláìmoye, ẹ̀yin aláìgbọ́n, jíjókòó tí mo jókòó, n kò jókòó ní ìjókòó ọba ni, tàbí aṣọ tí aṣọ tí mo wọ̀ ni kò tó ti ọba? Bí ẹ kò mọ nǹkan ẹ ko mọ iyì ìbàǹtẹ́ mi? Bí ojú yín tilẹ̀ fọ́ ẹ ó sọ pé ẹ kò rí adé mi ni? Bí ẹ kò tilẹ̀ mo gbogbo rẹ̀, ẹ kò rí aafin mi tí ó lókìkí jákèjádò ayó? Ọba wo ló tó mi? Ènìyàn wo ló gbọn bí èmi? Ta ni ọba náà láyó yìí tí ó lè fi ọwọ sọ àyà pé ìlú òun dárá bí ìlú mi? Ẹ̀yin ti ẹ lójú tí ẹ kò lè fi ríran- bí ẹ kò bá sọ́ra yín n oo báa yín jà kí ẹ tó kúrò ní ìlú mi. Báyìí ni ọba náà sọ, ẹ̀rù sì ba gbogbo wa pé bí ìlú rẹ̀ ti bàjẹ́ to nì, ó dárá lójú ọba! Ọjọ náà ni mo sì tó wá mọ̀ pé òmùgọ̀ tí ó ta gbogbo òmùgọ̀ yọ ni kí ẹni tí ó gọ̀ rò pé òun gbọ́n, nítorí ìgbà tí ènìyàn kò bá gbọ́n ṣùgbọ́n tí kò mọ̀ pé òun kò gbọ́n, àti gbe ọgbọ́n ẹlòmiràn kò ní ṣàì jẹ́ iṣoro. Nígbà tí ọba parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí mo ń fẹ́ sọ̀rọ̀ ni Ayédèrú-ẹ̀da dìde o ni òun ń fẹ́ sọ̀rọ̀ fún un, nígbà tí o sì máa sọ̀rọ̀ ó ni; Kábíyèsí inú mi dùn láti mọ̀ yín lónìí. Ẹ ma ṣe bínú pé a kò mọ yín nígbà tí a dé, kì í ṣe gbogbo wa ni kò mọ̀ yín, nítorí èmi ti mo dúro yìí, rírí tí mo ti rí yin ni mo ti mọ̀ pé ọba pàtàkì ni ẹ jẹ́. Ìlú yìí lè ṣàì dára lójú ẹlòmmíràn, ṣùgbọ́n èmi ni tèmi, mo gbáduǹ ìlú yin n kò sì sí nínú àwọn ẹlòmíràn tì ń sọ̀rọ̀ yín lẹ́yìn pé ìlú yìí kò dára. Ọ̀rẹ̀ yin ni mo fẹ́ ṣe. Mo kí yin mo tún yín kí, ẹ kú ìnáwo àáfin yìí, ẹ kú ìtọ́jú ìlú yìí, ìlú yìí jọ mi lójú, ẹ máṣe bínú sí mi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi o, Kábíyèsí. B;ayìí ni ọ̀kàn nínú wa sọ̀rọ̀, Ayédèrú-ẹda tí o ṣe mi ní àlejò ní ìlú rẹ̀ ní ìjọ́sí tí mo sì fi ṣe ìgbá kejì mi ni ìrìnàjò sí Igbó Elégbèje yìí. Kí Ayédèrú-ẹ̀dá tó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán ni púpọ̀ nínú wa tí a ti jókòó le orí ogiri kekere tí o yí ilé Òmùgọ̀diméjì po ti n fẹ́ sọ̀rọ̀. Ìgbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, Filásayépọ̀ dìde pọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Èmi pàápàá ń fẹ́ sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n nígbà tí mo rí àwọn ẹnìkejì mi gbogbo tí wọ́n sìde èmi jókòó mo sì wí fún Filásayépọ̀ àti Olójúmájèlé kí wọn jókòó kí wọn jẹ́ kí Kùmọ́diran sọ̀rọ̀, nítorí òun ló kọ́ sáajú gbogbo wa dìde. Nígbà tí Kùmọ́dìran bẹ̀rẹ̀ síí sọ̀rọ̀, àyà mi já, ó sọ̀rọ̀ yánna yànna ó ni: Òmùgọ́diméjì, inú mi kò dùn láti mọ̀ ọ́ rárá. Dídùn báwo? Iwọ, Òmùgọ́diméjì, ẹni tí o pè ọ ní Òmùgọ̀diméjì kò pè ọ́ bí o ti yẹ kí ó pè ọ. Nítorí kí ni n kọ, nítorí òmùgọ̀ rẹ rékọjá méjì, òmùgọ̀ rẹ ju méjì lọ. Bí òmùgọ̀ rẹ kò bá rekọja méjì, ìlú rẹ a bàjẹ́ tó báyìí lójú ara rẹ, ìwọ a tún máa rí ẹnu sọ̀rọ̀! Ìwọ alákọrí yìí, tí o ṣse ikùn bí àpò èkùrọ́. Ìbàntẹ́ wo lo fi ń ṣe fáàrí? Ìbàntẹ́ ni ọba ń sán? Fìlà rẹ gbọọrọ, bí ojú rẹ kò bá fọ́, fìlà rẹ tí ìwọ ń pè ní odé yìí dára ju fìlà orí awa lọ? Òní yìí ló di odidi ọjọ́ méje ti a ti ń ránṣẹ́ sí ọ pé kí jẹ́ kí á wá rí ọ, gbogbo àdéhùn tí o ń bá wa ṣe ni ò ń yẹ̀, síbẹ̀ o kò ronú ara rẹ wò. Èmi ni mo wí fún ọ, Òmùgọ́diméjì, bí etí rẹ kò bá di, gbọ nǹkan tí a máa bá ọ sọ lónìí: Ìlú rẹ yìí bàjẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí n kò rí irú rẹ̀ rí. Ayé ti kúrò ní ibi ti ẹ̀yin wà yìí, o nílati lọ múra kí o tún èrò ara rẹ pa. Ọ̀rọ̀ pàtàkì ni a wá láti bá ọ sọ lónìí, bí o fẹ́ bí a kọ̀ o nílati gbọ́ ọ̀rọ̀ náà bí o ko bá sì gbọ́ ní ojú bọ̀rọ̀, a o wí fún ọ ni ojú líle. Ọ̀rọ̀ tèmi kò jù báyìí lọ Báyìí ni Kùmọ́dìran parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, nígbà tí ó sọ ọ tán mo ṣàkíyesí pé inú àwọn ènìyàn mi dùn ṣùgbọ́n ẹru ti ń bà mí bí o ti ń sọ̀rọ̀ náà bọ̀ kí ìjà má ba bẹ́ sílẹ̀ nígbà tí o parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, nítorí ọ̀rọ̀ tí ó sọ le, ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé nígbà tí Kùmọ́dìran parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀rín ni ọba Òmùgọ̀di-méjì bú sí, ó rẹ́rìn-ín títí o fi yí lulẹ̀ lórí ogiri kékeré tí ó jókòó lé nígbà tí o sì dákẹ́ ẹ̀rín náà ṣe ló kọjú sí ọkùnrin tí ó dé bá wa níbẹ̀ tí ó wí fún un pé kí o mú wa lọ sí ààfin kí a lọ jókòó de òun, òun ń bọ. Bí wọ́an ti ṣe ètò ilé Òmùgọ̀diméjì yàtọ̀ púpọ̀ sí tí ilé àwọn ọba tí mo mọ̀. Ṣe, ni ààfin ìlẹ̀ Yprùbá, inú ààfin pátápátá lọ́hùn-ún ni ilé àwọn ayaba ń wà, kò rí bẹ́ẹ̀ fún Òmùgọ́diméjì, ilé àwọn obìnrin rẹ̀ ló kangùn sí ibi tí ènìyàn ń gbà wọlé, nígbà tí wọ́n sì mú wa wa ilé, ilé àwọn obìnrin ni wọ́n mú wa wọ̀ lọ. Gbogbo àwọn obìrin náà wà ní ìhòòhò, wọn ń wọlé wọ́n ń jáde. Mo rí ọgbọ́n díẹ̀ kọ́ nibi tí a jókòó sí yìí nítorí kò pé tí a dé tí àwọn mẹ́ta kan fi dé wá bá ni, mo sì fetí sí ohun tí wọn ń sọ nípa ọba wọn. Òmùgọ̀diméjì kò náání ẹlòmíràn àfi àwọn ìjàyè nìkan láàrin ìlù titi kan àwọn olówó àti àwọn ẹlòmíran gbogbo tí ẹnu wọn tó ilẹ̀ láàrin ìlú, kò fi tiwọn ṣe nígbà tí wọn kò ti sí ní ìgbìmọ̀ kí wọ́n máa tìí lẹ́yìn nínú ẹjẹ́ tí o ba ń dá. Nítorí èyí, àṣírí ọkùnrin náà kò le bò, àwọn ẹlòmírán ń bẹ láàrin ìlú tí wọ́n ju ìjoye lọ, yálà ni ipa ọgbọ́n, yálà ni ipa ìmọ̀, yálà nípa owó, yálà nipa aáṣíkì. Bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ kí ẹni tí ó bá jẹ́ olórí ìlú máa fa gbogbo ayé mọ́ra. Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀ tí a ti dé ààfin ni ọba ránṣẹ́ sí ìyàwó rẹ̀ à gbà kí ó fi ilé òun hàn wá. Obìnrin náà sanra báyìí ó wà ní ìhòòhò gidigidi. Ó mu wa yí ilé náà po ṣùgbọ́n èyí tí ó yà wá lẹnu jù níbi tí o ti n mu wa ká ni pe ìgbà tí a wọ inu iyààrá kan, kò sí nǹkan tí ó kù níbẹ̀ tí kò ni fi han ni. Bí o bá rí owó nínú àpótí a ka gbogbo rẹ̀ fún ni, ìgbà tí o mú wa dé ibi tí wọ́n ti ń ṣe igbọ̀nẹ̀ o tun ń fẹ lọ fi Ìgbọ̀nsẹ̀ gan-an han ni, a bá kọ̀ fún un. O àti lọ́wọ́ ẹni tí ó ti yáa, ó dárúkọ àwọn tí ọba gbà gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá àti àwọn tí ó gbà gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́. O sì sọ èrò gbogbo gba nípa àwọn ìjòyè rẹ láì ku ẹyọ kan nínú wọn. Ó fi ilé oúnjẹ hàn wá, o fi ìkòkò ọbẹ, o ka iye ekìrì ẹran tì o kù nínú gbogbo ìṣaasùn ọbẹ̀ fún ni. Ó dárúkọ gbogbo ìyàwó ọba hàn wá, ó sọ bí ilé ìyá àti bàbá oníkálùkù ti rí àti bí ọba ti fẹ́ràn olúkúlùkù tó, nígbà tì ó sì tún n tú àṣíírí ọkọ rẹ̀ báwọ́n-ọnnì mo wí fún un kí ó yé sọ gbogbo nǹkan wọ̀n-ọnnì fún wa ṣùgbọ́n ó wí fún mi pé bẹ́ẹ̀ ni baálé òun ní kí òun máa ṣe. Nígbà tí a yí ilé náà po tán tí a padà dé ibi tí a ti kọ́ jókòó, a rí i pé ọba kò tíì wọlé. Ìgbà tí o sì pẹ́ tí a ti jókòó ni obìnrin kan pe ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé náà pé kí ó pe ọba wá wí pe iṣu tí òun ṣe ti jiná kí ọba wá gún iyán ní ẹ̀yìnkùnlé. Nígbà tí o ṣe a kò gbọ́ ọwọ́ odó mọ́, kò sì ju ìṣẹjú kan tí ọwọ́ odó dákẹ́ tí ariwo ta ni ẹ̀yìnkùnlé pé ọba ń jà tí a bẹ̀rẹ̀ síí gbọ́ gìrìgìrì ẹsẹ̀. Wéré a sáré lọ sí ibẹ̀, nígbnà tí a sì máa dé ọ̀hún ìyàwó ọba ti gbé ọba lulẹ̀, orí rẹ̀ ni a sì ti bá a tí o ní gbá ọba létí léraléra, a bá mu wọn ti a gba ọba lọ́wọ́ rẹ̀. Ìgbà tí ọba tún dìde tan, o ni àfi bí òun tún jà si i àti pé bí kò ba ṣe pé a tètè mú àwọn ni, òun ìbá yí obìnrin náà kúrò lórí òun, eléiìí náà ni a sì ń sọ tí ó já ọwọ́ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ wa tí ó tún pa guuru sí obìnrin náà, kí á tó tún ṣẹ ojú pẹ́, ìpàkọ́ ọba ni a tún ń wò ní ilẹ̀, àwọn ará ilé ọba tún mú wọn. Ìgbà tí ó sì jẹ́ pé ọba kò dákẹ́, ìjà tún bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kẹta, obìnrin yìí tún yí ọba mọ́lẹ̀. Ki n ma sà bá ọ̀rọ̀ yìí lọ bí ilẹ̀ bí ẹní, èèmeje ni obìnrin yìí gbé Òmùgọ̀diméjì lulẹ̀ lójú wa, ìgbà tí wọ́n sì jàjà gba ọba sílẹ̀ lẹ́ẹ̀keje yìí ṣe ló gba iré dà sílẹ̀ tí obìnrin yìí náà gbá tẹ̀lé e. O lé e pẹ títí kí ó tó padà lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí obìnrin yìí padà tán, gbogbo wa tọ ọba lọ sí ibi tí ó dún sí, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a gbọn ìpàǹtí orí rẹ̀, àwọn ìpàǹtí tí ó dì mọ́ ọ lórí gbogbo ní ibi tí obìnrin náà ti ń gbé e yílẹ̀. Ọba pàápàá fi ọwọ́ gbọn erùpẹ̀ tí ó lè mọ́ ọ lára àti ní ìdí tí o mú kí ìdí rẹ di pupa. Ibi ti a ti n ṣe eléyìí ti à ń kí ọba ni ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè rẹ̀ ti dáhùn tí ó ni, ‘Kábíyèsí, kò nà yín tó ti ijọ́sí lónìí.’Ọba náà sì fèsì ó ni, Bẹ́ẹ̀ ni, mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ ọwọ́ obìnrin náà ni, nítorí mo gbé e lẹ́ẹ̀kan bí ẹni kí n là á mọ́lẹ̀ àfi ìpàǹtí tí ó kọ́ mi lẹ́sẹ̀ ló jẹ́ kí o bọ́ lọ́eọ́ mi’Ẹnìkan tún bèèrè ó ni, ‘ṣé kò ta yín ní ìpá lónìí?’Òun náà sì tún dáhùn ó ni, ‘Ó ta mi ní ìpá díẹ̀, ṣùgbọ́n ẹsẹ̀ rẹ̀ kò bá mi ni ibi burúku.’ Ọ̀kan tún ṣe ìbéèrè ó ni, ‘Adé yín dà?’ Ọba tún dáhùn o ni, ‘Ibi tí o ti ń nà mì ni adé mi ti ṣí bọ́ sínú odó, n kò tilẹ̀ mọ ibi tí ó wà báyìí.’ Lẹ́yìn èyí ni Kùmọ́dìran ṣe ìbèérè tí ó ni, ‘Báwo ni ìjà náà tilẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀? Òun náà sì wá sọ ó ní, ‘Bí mo ti n gún iyán ni obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí bú mi tí o wí pé ọwọ́ mi kò ran odó iyàn, èmi ń gún iyán tíẹ́típẹ́, àti pé ẹnu ni èmi lè máa fọ́n kiri, kò sí nǹkan kan tí mo lè ṣe ni mo bá ni kí ó yé bú mi, n kò wí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àfi “gbàì” tí mo ggbọ́ létí mi tí ó gbá mi létí, ni mo bá bẹ̀rẹ̀ ǹjẹ́ ki n kó o lẹ́sẹ̀ kì n nà án mọlẹ̀ ní ògèdèǹgbé, bí mo ti bẹ̀rẹ̀ báyìí’, ṣe ló gbe mi ní ìpá tí mo fi orí na ọlọ ata. Ọ̀rọ̀ kékeré lẹ pè é, díẹ̀ ló kù kí obìnrin náà fọ́ mi lórí, ṣe lorí ń ta mí fòò bí mo ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ṣùgbọ́n kò yà mí lẹ́nu, bẹ́ẹ̀ ni ìyá rẹ̀ ń fọ̀ bàbá rẹ̀ lórí tí wọ́n fi sí ẹ̀wọ̀n, ìdílé fọ́rífọ́rí ni ìdílé wọn.’ Èmi náà wá dáhùn mo ní, ‘Ìgbà tí ẹ mọ̀ pé ìdílé burúkú bẹ́ẹ̀ ni ìdílé wọn ki ní ṣe tí ẹ fi fẹ́ ẹ? Ó fèsì ó ni, ‘O kò rí i pé ó lẹ́wà ni? Jẹ́ ki n sọ fún ọ, òun pàápàá ti wọ ẹ̀wọ̀n lẹ́ẹ̀méta, ọ́jọ̀ kẹta tí ó jáde lẹ́wọ̀n ẹ̀ẹ̀kẹta ni mo fẹ́ ẹ, ó wù mi gan-an ni.’ Ibi tí a ti ń sọ èyí ni ẹnìkan ti ti òde wọlé tí ó ní òun ń bá ọba kẹ́dùn ó ni, ‘Kábíyèsí ẹ kò lọ túbọ̀ múra? Ẹ kò lọ múra? – Kí obìnrin má a na olúwarẹ̀ lójóojúmọ́ báyìí! Ojú máa ń ti awao. Ìgbà tí ọba gbọ́ bẹ́ẹ̀ ó dáhùn pẹ̀lú ìbínú ó ni, ‘Bí ojú ba lè tìyìn kó máa tìyìn , bí ẹ kò bá ni bí ó ti ga sókè fíofío ni.’ Ìgbà ti Fìlásayépọ̀ sì wí báyìí pé, Ìgbà tí ẹ mọ̀ pé ipá yín kò níí ka, ki ni ẹ fẹ́ ẹ sí? ọba tún bínú, ó ní, ‘mo ti sọ fún alákọrí yín lẹ́ẹ̀kan pé ó wù mi ni.’ Lẹ́yìn èyí Ayédèrú-ẹ̀dá sọ̀rọ̀ o ní, ‘Mo mọ̀ dájú ṣá pé bí obìnrin náà bá tún dé ẹ ó ba a fi ìjà pa ẹẹ́ta.’ Òmùgọ́diméjì náà wa rọra rẹ́rìn-ín díẹ̀ báyìí ó ní, ‘Dájúdájú, bí o bá tún lè yọ sí mi n ó lù ú, n ó fẹ́rẹ̀ pa á nítorí, mo ti mọ ọwọ́ rẹ̀ nísisì yyìí, n kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ rárá, n kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ rárá, bí ẹ ti ń wò mi yìí o, ẹ máṣe fi ojú di mi o, tàbí ẹ rò pé ọkọ yẹpẹrẹ kan lásán ni mi ni? – ó mà tì o, kìí ṣe bẹ́l rárá, tàbí ẹ kò ní i bí mo ti pọn ìkólóbo dan? Abbl... Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ọba náà kòì tíì sọ jù báyìí lọ àfi ìgbà tí ẹnìkan déedée kígbe, ‘ó dé, ó dé, obìnrin náà tún dé o!-‘kí ni ọba gbọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe Òmùgọ̀diméjì gbé iré dà sílẹ̀, ìyàwó fi tẹ̀lé e, ọ̀ràn di ‘Bóò lọ yá fún mi, nígbà ti gbogbo wa sì ń wo ìpàkọ́ ọba báyìí ẹ̀rín la bú sí, a rẹ́rìn-ín títí àrín-tàkìtì ni- bẹ́ẹ̀ ni ìpàkọ́ Òmùgọ́diméjì ṣe bí ẹnií gùn díẹ̀ báyìí, ó sì tún wá tẹ̀ díẹ̀, ó rí kọnkó. Ibi tí o ti ń sálọ, ìbàntẹ́ tu, ó wá fi ọwọ́ mú ìbàǹtẹ́ mọ́ ìdí, okùn eléyìí ní n fì dìròdìrò. Nígbà tí ó pẹ tí obìnrin náà padà lẹ́yìn ọba, a lọ bá a níbi tí ó sá pamọ́ sí nígbà tí a sì báa sọ̀rọ̀ ó ju ọwọ́ sí wa o ni kí a rọra máa sọ̀rọ̀ kí ẹni ti o ń lé òun má ba à gbọ́. A wí fún un pé à ń fẹ́ lọ sí ibùdó wa àtipé a kò rò pé a lè sọ̀rọ̀ tí a bá wa mọ́ lákòókò náà. Òun náà gbà bẹ́ẹ̀ fún wa, o ní kí a padà wá ní ojú alẹ́. Báyìí ni a fi ààfin ọba àwọn Èdìdàrẹ́ sílẹ̀ tí a wa sí ibùdó wa. Nígbà tí ó di ojú alẹ́, a wá sí ààfin, ìgbà tí a sì máa dé ọ̀hún ìjà náà ti rọlẹ̀, ọkàn ọba pàápàá ti balẹ̀, o sì fetí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí a bá a sọ, ṣùgbọ́n ọba náà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá wọ̀n-ọnnì tí wọ́n máa ń jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara wọn, tí wọ́n máa ń jiyàn dé gongo lórí nǹkan tí kò yẹ kí ènìyàn jiyàn lé, wọ́n kìí fetí sílẹ̀ kí wọ́n gbọ́ ìmọ̀ràn ẹnìkejì, wọ́n a má le koko lórí ohun ttí kò yẹ. Nígbà tí a wí fún Òmùgọ́diméjì pé Ilẹ̀ẹ́gbóná kò dára, ó ní ó dára ní ti òun, àti pé òun níí mú ara ènìyàn le, àti pẹ̀lú pé bí Ilẹ́ẹ̀gbóná kò bá tíì mu ènìyàn olúwarẹ̀ kò tíì bọ́ sínú ayé. Ìgbà tí a ni kò yẹ kí gbogbo ènìyàn máa fara mọ ẹni tí ilẹ̀ẹ́gbóná b’’a ń ṣe bbí a ti ń rí wọn tí wọn ń ṣe wọ̀n-ọnnì, ó ní òun gan-an ló yẹ, ìgbà tí a wí pé èérí ìlú náà pọ̀ jù àti pé bí wọ́n ri ṣe n kọ́ ilé wọn ni o ń mú àìsàn dé bá wọn, ó ní irọ́ ni a ń pa. Ó yà mi lẹ́nu púpọ̀ pé ogunlọ́gọ̀ lóde ayé koi tii mọ̀ nípa pé kí a máa bu apa fún ni kí Ifẹ̀ẹ́gbóná má ba ṣe ni, ni àwọn Èdìdàarẹ́ ti mọ̀. Bí ìtàn náà tì lọ nì yí. Ní ayé àtijọ́, ọkan nínú àwọn ìráńṣẹ́ Olódùmarè a máa yí ayé po lọ́dọ́dún, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ìmọ́lẹ̀. A maa yí ayé po láti wá wò bí àwọn aráyé bá tì ń ṣe. Ìgbà tí ó ba ń lọ a máa yí ara padà sí bí ó bá ti fẹ́ ni, ìgbà mìíràn a wá bí ọmọ kékeré ìgbà mìíràn a wá bí àgbàlagbà. Ní ọdún kan, nígbà tí ó wa, o sọ ara rẹ̀ di arúgbó kù jù ọ̀, ó sì gbé erù lórí, ó dúró sí ẹ̀bá ìlú àwọn Èdídàrẹ́, nígbà tí ọmọ ọba ń lọ sí oko tí ó rí i, wọ́n kí ara wọn, arúgbó yìí sì wí fún un kí ó bá òun gbe ẹrù òun díẹ̀. Ọmọ ọba yìí kò jà á ní iyàn rárá ó bá a gbé e-wọ́n jọ ń lọ. Nígbà tí o ṣe, wọ́n dé ibi odò kíkùn kan, ọmọ ọba gbé ẹrù kọjá sí òdì kejì, àfi bí ọmọ ọba náà bá tún gbé òun, ọmọ ọba ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbà tí wọ́n wá dé òdì kejì náà wàyí ò, ni ìráńṣẹ́ Olódùmarè yí ara padà tí ó funfun báláú tí ó ga fíofío, ó dáhùn osì wí pé, ‘Nítorí ìwọ ṣe mi lóore yìí, láti òní lọ n o máa ránṣẹ́ wa láti òde ọ̀run ní ọdọọdún kí kí àwọn ìrańṣẹ́ mi máa sín yín ni gbẹ́rẹ́, kí kí Ilẹ̀ẹ́gbóná ma ba à bá yín jà mọ́, yóò sì ṣe, ẹni tí ó bá fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún gbẹ́rẹ́ sín sín yìí, kì yóò rí ìjà ṣọ̀pọ̀nnà bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ ń kú bẹẹrẹ. Báyìí ni ìtan apá tí wọn n bù ṣe lọ ‘A gba ọba náà ni ìyànjú pé kí o jẹ́ kí wọn bu apá fún òun ṣùgbọ́n gbangba ló wí fún wa pé òun ko níí jẹ́, a bá kúrò ní aafin. Nígbà tí o tó ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn èyí ti mo tún lọ sí ààfin ǹ jẹ́ kí n lọ bẹ ọba wo, bíbá tí mo bá a bà mi lẹ́rù lọ́pọ̀lọpọ̀, Ilẹ̀ẹ́gbóná ti bò ó, ṣe lo ń gbin ni ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìgbà tí mo kíi, kò lè dá mi lóhùn mọ́ àánú rẹ̀ sì ṣe mi. Kò ju ọjọ́ méje lẹ́yìn èyí tí a gbọ́ pé ọba náà kú. ÒMÙGỌ́DIMẸ́TA GORÍ OYÈ SỌ̀PỌ̀NNÁ GBÉ ÒMÙGỌ́DIMÉJÌ LỌ I bi tí àlejò mi sọ̀rọ̀ náà fún mi mọ lọ̀jọ̀ tí a tún kọ̀wé náà ni èyí, a bá dá ọwọ́ dúró lọ́jọ́ náà, a kí àwọn tí ó wá gbọ́ ọ̀rọ̀ wa pé kí wọ́n máa lọ sílé kí wọ́n tún padà lọ́jọ́ kejì. Kò pẹ́ púpọ̀ tí ilẹ̀ ọjọ́ kéjì sì mọ́ tí gbogbo ènìyàn tun fi ń rọ wọ ilé mi, ìgbà tí àwa náà sì jẹun tán, àlejò mi tún bẹ̀rẹ̀ o ń bá ìtàn náà lọ ó ni: Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ibi tí mo bá ìròyìn náà dé lánà ni ikú Òmùgọ̀diméjì. Bí àwọn Èdìdàrẹ́ ti ṣe lẹ́yìn ikú rẹ̀ yà mi lẹ́nu. Ìgbà tí mo lọ sí aafin, ṣe ni mo bá gbogbo wọn tí wọn ń yọ̀, ìgbà tí mo sì bèèrè ìdí ayọ̀ lọ́wọ́ ẹnìkan báyìí ó ni, ‘Gbogbo wa ń yọ̀ nítorí ẹran dé, ìdí Òmùgọ̀diméjì rí bẹ̀ǹbẹ̀ bẹnbẹ, ìkùn rẹ̀ yọ bọ̀ǹbọ̀ bọ̀ǹbọ, òun pàápàá tóbi ó rí yọ̀kọ̀tọ̀ yọkọtọ, ẹran ìbàdí rẹ̀ kò ní ṣàì ṣe sínkín sí wa lẹ́nu. Kò sí ẹni tí ó wà nínú àwọn Èdìdàrẹ́ tí ó fẹ́ kí òun pàápàá kú, ṣùgbọ́n olúkúlùkù ní inú dídùn sí ikú ọmọnìkejì rẹ̀. Ìlú burúkú gbáà ni. Ní ọjọ́ keje tí Òmùgọ́diméjì kú ni wọn fi àkọ́b;i ọmọ rẹ̀ joyè, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Òmùgọ́dimẹ́ta. Ní ọjọ́ kẹta tí Òmùgọ́dimẹ́ta joyè ni àwa náà múra tí a lọ̀ kí i gẹ́gẹ́ bí àlejò ní àgbègbè ibẹ̀. Ọjọ́ náà ni mo kọ́ mọ ìyá rẹ̀ ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìlábùrù. Wọ́n ṣe wá ní àlejò gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti gbọ́n mọ, nítorí awẹ́ obì kan ni Ìlábùrù fi fún gbogbo wa. Nígbà tí a kí i tán, a lọ kí àbúrò Òmùgọ́dimẹ́ta ẹni ti orúkọ rẹ ń jẹ́ Dánásungbó. Ọdún kan- àbọ̀ péré ni Òmùgọ́dimẹ́ta fi ju Dánásungbo lọ, ṣùgbọ́n ìkíni tí ó kí ni kò jọ ìkíni àbúrò ọba, dípò kí àwa dọ̀bálẹ̀ fun un, òun ló tún dọ̀bálẹ̀ fún wa, kò sì dọ̀bálẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ggbogbo wa lo kí lọ́tọ́ọ̀tọ̀ tí o dọ̀bálẹ̀ fún olúkúlùkù káàkiri. Ní àkókò tí Òmùgọ́dimẹ́ta fi ń ṣe tí oyè yìí mo bẹ ààfin wo tó ìgbà mẹ́ta, nítorí kò sí ìgbà tí mò ń dé òhún tí ìyá rẹ̀, Ìlábùrù ko ń kí mi dáadáa. Bí o ti wu tí obìnrin ṣe aláìgbọ́n tó, kò ní ṣàì fẹ́ràn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni bí a bá fẹ́ràn ọmọ ẹni, ọ̀rẹ́ ọmọ náà ọ̀rẹ́ ni yóò jẹ́ fún ni. Nígbà tí ó pẹ́ tí ọba tuntun yìí ti jẹ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìgbìmọ̀, ìgbà tí o sì di ọjọ́ kan tí mo lọ kì i, ó wí fún mi pé òun ń fẹ́ kí n wá wo bí wọn ti ń ṣe Ìgbìmọ̀ ìlú òun. Ó wí fún mi pẹ̀lú pé ẹsin ni a o jọ gùn lọsí Ìgbìmọ̀ náà láti ilé òun; nítorí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ra ẹsin méjì náà òun yóò sì kọ̀ gún ọ̀kan lọ́jọ́ tí a bá máa lọ kí èmi náà gun èkejì. A dá ọjọ́ lílọ. Nígbà tí ọjọ́ lílọ pé mo lọ sí aafin. Ìyàlẹ́nu lójẹ́ fún mi láti ri i pé nígbà tí ẹni ti ọba rán kí ó lọ mu ẹṣin wa máa yọ, màlúù ló mú wa. Nígbà tí mo ri i, mo wí fún ọba mo ni, ‘Ha! Ọba Èdìdàrẹ́, màlúù ni ẹ̀ ń pè ní ẹṣín! Ojú kò sì ti ọba níggbà tí mo wí bẹ́ẹ̀, ó dáhùn ó ni, òhun tí àwọn ń pè ní ẹṣin ní ìlú awọn ni èyí nì. Wéré ọba tọ lé ọ̀kan nínú àwọn màúù wọ̀n-ọnnì, ìgbà tí màlúù ju orí, ẹ̀yìn ọba, ilẹ̀ lo lọ, màlúù ní igi. Èyí kọ́ èmi ní ọgbọ́n, nítorí náà n kò gun màlúù ní tèmi, ìgbà tí ọba sì rá pálá dide tan ó tún tọ lé màlúù lẹ́yìn ó ń lọ pẹ̀lú hílàhílo. Nígbà ti a dé ìgbìmọ̀ ní ọjọ́ náà, a bá àwọn ènìyàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ tí wọn ń sá kiri nínú ilé náà. Ìgbà tí èmi àti ọba sí wọlé, wọn kò dákẹ́ rárá, ẹnìkan kò tilẹ̀ sọ pé òun rí wa ṣùgbọ́n nígbà tí ọba kígbe sókè, tí ó dìde dúró, tí ó ní kí àwọn ka ìgbàgbọ́ nípa oúnjẹ, ṣe ni gbogbo wọn dákẹ́ minimini. Òkú oúnjẹ ni wọ́n, èmi pàápàá kò gbọ́ ìgbàgbọ́ oúnjẹ rí, ọjọ́ náà ni mo kọ́ gbọ́ ọ, n ó máa kà á nísisì yìí, kí ẹ̀yín náà máa kà á tẹ̀lé mi. Mo gba oúnjẹ gbọ́, òun ni alákòóso ara, oúnjẹ didára mú ara dan, a máa mú egungun le, ẹ̀jẹ̀ a sàn ká koko, àìdára oúnjẹ ni ń fa àìsàn lẹ́sẹ̀, ìjẹkújẹ oúnjẹ, o ń sọ ara di arúgbó, èrẹ̀kẹ́ a di palaba, ojú á di foforo, imú á di tọgíla, ẹsẹ̀ a di tín-ín-rín, apá á di jawala, iwájú a di gọnbu, ìdí á di pẹlẹbẹ, gbogbo àwọ̀ ara a rí kùọ̀kuọ. Mo sì gbàgbọ́ pẹ̀lú pé, nínú ìpàdé oúnjẹ, iyàn á ṣe alága, àmàlà á ṣe igbákejì, ìrẹsì ni ìgbá kẹta, ẹ̀kọ ni aṣáájú, ó sì kẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ṣùgbọ́n ọbẹ̀ ni ọlọ́pàá, òun ni atọ́kùn òkèlè, gbà tí iyán gbéyàwó, ọbẹ ilá ni ìyàwó, gbà tí àmàlà lóbìnrin, ewéédú lobìrin, ẹ̀fọ́ laya àkàṣù, mọ́ínmọ́ín arẹwà, olùfẹ́ ẹ̀kọ mímu, dodo náà kò rẹ̀yìn, baálẹ̀ ìgbèríko, dùǹdú kò kéré, ó jọba sí ìletò, kakaǹfòi níbẹ̀pẹ, ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹẹrẹ laṣipa, ìgbà tí gaàrí ń ṣọdún ó pe eja sípàdé, ó pe ẹran. Sí ìpàdé, o pe edé sí ìpàdé, ó pe ìlá sí ìpàdé, ó tún pewéédú sí ìpàdé, bẹ́ẹ̀ ni o gberaga bẹ́ẹ̀ ni, àjejù kò sunwọ̀n, ìwọ̀ntunwọ̀nsì ló dára. Alágbára ni ata, alùbọ̀sá gbajúmọ̀, bọ̀ọ̀kìní tòmáàtì, ọlọ́rọ̀ ni ègúsí. Lórí gbogbo ìwọ̀nyí, oúnjẹ dáadáa, ommì dáadáa, atẹ́gùn dáadáa, ni ń ṣe ara dáadáa. Báyìí ni àwọn Èdídàrẹ́ ka ìgbàgbọ́ wọn lórí oúnjẹ. Nígbà tí wọn ń ka ìgbàgbọ́ yìí ẹníkẹ́ni kò sọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ṣùgbọ́n wéré tí wọn kà á tán ni wọ́n ti tún bẹ̀rẹ̀ ariwo. Àwọn Èdìdàrẹ́ bu ọlá fún oúnjẹ ju ọba wọn lọ. Mo sì fẹ́ kí ẹ ṣàkíyèsí pé òótọ́ ni gbogbo nǹkan ti w\\on s\\o nípa òunjẹ, o fi han ni pé nǹkan tí ènìyàn bá ń fẹ́ láti mọ, yóò mọ̀ ọ́, àwọn Èdìdàrẹ́ gọ̀ wọ́n bàjẹ́ ṣùgbọ́n wọ́n kọ́ ẹ̀kọ́ nípa oúnjẹ. Wọ́n kò da ẹjọ́ púpọ̀ lọ̀jọ̀ tí mo ń sọ̀rọ̀ yìí, ṣùgbọ́n èyí tí wọ́n sì dá, ẹjọ ọba pàápàá ni. Ọkùnrin kan gba mẹta ninú àwọn ìyàwó ọba, àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta sì wa síwájú ọba, wọnh ń ro ẹjọ ara rẹ̀ fún un. Wọ́n sì bù u ṣàkà báyìí lójú mi, bẹ́ẹ̀ ni òun ni yóò dá ẹjọ́, o sì yà mi lẹ́nu pé ojú gbogbo wa báyìí ni ọba ṣe ń bẹ wọ́n kí wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ òun. Bí ó ti wí báyìí ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tí ó gba ìyàwó mẹ́tẹ́ẹ̀ta bọ́ síwájú ọbha tí o ń bú ọba pé wọnn kò níí padà, owó ọba ni wọ́n máa san. Ìgbà tí ọba rii pé àti pada jẹ́ ìṣòro, ó gba kọ́bọ̀ kọọkan lórí ìyàwó kọọkan, gbogbo rẹ̀ jẹ́ tọ́rọ́-bẹ́ẹ̀ ló sì wá jẹ́ pé tẹ́rẹ́ lowó obìnrin mẹta ni ìlú àwọn Èdìadàrẹ́. Ẹjọ́ tí wọ́n ṣe tẹ̀lé èyí, ẹjọ́ ọba ni, ẹnìkan sọ pé bàbá ọba, èyí nì ní Òmùgọ́diméjì, ti jẹ òun ní owó kan kí ó tó kú, pé owó náà jẹ́ kọ́bọ̀ mẹ́rin ó sì fi jàgùdà-páálí lé e pé àfi bí ọba bá san owó náà fún òun ní wéréwérré. Ọba ba mu tọ́rọ́ tí ó gbà lórí àwọn ìyàwó rẹ̀, ó kó o fún un, owó wá ku kọ́bọ̀ kan láti san, ojú mi báyìí ni ọba ṣe ń wa owó yá tí kò rí ẹni yá a ní kọ̀bọ̀ kan, ojú mi báyìí náà sì tún ni ẹni tí o ni owó yìí ṣe lọ sí ọ̀dọ̀ akọ̀we Ìgbìmọ̀ tí ó ní kí ó fún òun ni ìwe ẹjọ́ kí òun fi bá ọba ṣe ẹjọ́ náà. Ojú mi náà báyíí ni akọ̀wé sì fi fún un ní ìwe. Nígbà tí wọn fún ọba ní ìwé ìpẹ̀jọ́, ọba dọ̀bálẹ̀ láàin ìgbìmọ̀, ó bẹ ọkùnrin náà. Onítọ̀un sì wí fún un pé òun fún un ní ọjọ́ mẹ́ta kí o fi máa wá owó náà kiri, àti pé bí kò ba riri, òun ó pèé ni ẹjọ́ ẹ̀wọ̀n. Báyìí ni mo dé ìlú àwọn ÈDìdàrẹ́ ní ibi tí wọn ti ń pè ọba lẹ́jọ́ kọ́bọ̀ kan. Nígbà tí a kúrò ní ìgbìmọ̀, mo padà lọ sí ibùdó wa, mo ròyìn ohun tí mo rí fún gbogbo wọn. Ṣùgbọ́n ó yà mi lẹ́nu púpọ̀ bí Aláyélúwà ọba Ọmùgọ́dimẹ́ta ṣe hùwà lẹ́yìn èyí. ṣe ẹni tí o ba n rí èmi àti òun bí a ti jọ n rìn, kò ni sàì ní èrò pe a n bẹ̀rẹ̀ ọ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ kọ́, Òmùgọ́dimẹ́ta kò mọ ìyí mi rárá. Kò sì jọ mi lójú pé ó rí bẹ́ẹ̀, nítorí bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlìmíràn wà ní òde ayé tí wọn ń jẹ́ orúikọ mìíràn ṣùgbọ́n tí ìwà wọn bá tí Òmùgọ́dimẹ́ta mu. Àwọn eléyìí ni ẹni ègún, tí wọ́n ṣẹ̀ sí Olódùmarè wọ́n sì ṣẹ̀ sí ènìyàn pẹ̀lú, bí ẹnìkan bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, dípò kí wọn túbọ̀ máa gbé e ga, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọmọ Olódùmarè ní ijọ́sí, wọn a fi olúwarẹ̀ sí abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ wọn, wọ́n á gbé ẹsẹ̀ wọn sókè, wọ́n a gbé lọ̀ ọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní lè dúró láàrin àwọn èrò iwájú, ààrin èrò ẹ̀yìn ni wọ́n ó máa wà láéláé. Kí ni mo máa rí, Òmùgọ́dimẹ́ta lọ ṣe ofin tí o fi hàn gbangba pé èmi àti àwọn ẹlẹgbẹ mí ni o ń fẹ́ ṣe ní ibi àwọn ofin náà ni ìwọ̀nyí: ‘Ofin kín-ín-ní: Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí Ìrìnkèrindo nílati nà án ní kùmọ̀ lẹ́yìn ọrùn, ẹni tí ó bá rí ọkùnrin náà tí kò fọ ọ ni kùmọ̀ dáadáa, olúwarẹ̀ ìbáà ṣe ọkùnrin, ìbáà ṣe obìnrin nílati san kọ́bọ̀ márùn-ún. Mo fẹ́ kí ẹ wo bi ìkórìíra náà ti tó, ọba tí wọ́n ní kí ó san kọ́bọ̀ kan tí kò rí, wá sọ pé ẹni tí kò bá fọ èmi ní kùmọ̀ dáadáa nílati san kọ́bọ̀ márùn-ún owó obìnrin márùn-ún ní ìlú Èdìdàrẹ́! Ofin méjì tí ó ṣe ni ó bá wa wí, èkejì sì ni èyí: ‘Àlejò kálejè tí ó bá wọ ìlú kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ ará rẹ̀, oúnjẹ àwọn Èdìdàrẹ́ lo níláti rà jẹ́ kò gbọdọ̀ mu omi ibòmíràn, omi àwọn Èdìdàrẹ́ lo nilati mu, kò gbọdọ̀ gbé ilé ara rẹ̀, ilé àwọn Èdìdàrẹ́ lo nílatí gbe. Ẹni tí ó ba lu ofin yìí yóò wọ ẹ̀wọ̀n ìṣẹ́jú mẹ́wàá.’ Ìgbá tí Òmùgọ̀dimẹ́ta parí àwọn òfin yìí tán ó parí wọn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Èmi, ọba ńlá, tí ó ju gbogbo ọba lọ, Aláyélúwà Òmùgọ́dimẹ́ta ọba èdìdàrẹ́, tí Ìlábùrù bí fún Òmùgọ́diméjì, baba Dánásungbó, mo fi ọwọ àti ẹsẹ̀ mi, ojú àti imú mi, orí àti ọrùn mi, inú àti ẹ̀yìn mi, orí ahọ́n àti ihò imú mi, sí ìwé yìí, ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀sán, oṣù kẹfà, ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá ọdún ó le méjìlá méjìléláàdọ́tá lẹ́yìn ikú Olúwa wa. Nǹkan tí mo ṣa fẹ́ kí ẹ mọ̀ ni pé a níláti bá àwọn Èdìdàrẹ́ jagun gan-an lé orí òfin yìí, n kò lè ròyìn ogun náà fún yín, nítorí àkókò ń lọ, ṣùgbọ́n a ṣẹ́gùn, wọn túúbá fún wa, wọ́n ní àwọn di tiwa. A bá àwọn ìjòyè ìlú náà ṣe àdéhùn, wọ́n sì fi ọwọ́ sí ìwé pẹ̀lú wa pé àwọn di tiwa. Ohun kín-ìn-ní tí a kọ́ ṣe ni pé a wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ́ àti àdá pẹ̀lú àáké a kó o fún wọn kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ si i ṣe iṣẹ́ àti tún ìlú ṣe. Wọ́n ro oko gbogbo tí ó wà ní ìgboro, wọ́n ṣe ojú ọ̀nà dáadáa, a mu kí wọ́n ṣe ilé ìgbọ̀nṣẹ̀, gbogbo àwọn igi tí o wà láàrin ilú tí ó mú kí ìlú dàbí inú igbó la mú kí wọ́n ge, wọ́n tún odò gbogbo ṣe. A wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ àti kànìn kànìn fún wọn kí wọn fi wẹ̀, a sì ṣe òfin pé olúkúlùkù níláti fi ara hàn ni bí ó bá tì wẹ̀ tán. Báyìí ni a tún ìlú wọn ṣe. Mo rò pe ẹ o fẹ́ láti mọ bí a ti ṣe ọba wọn sí, yálà a fi ọba mìíràn jẹ ni tàbí a kò fi jẹ. A kò fi ọba mìíràn jẹ, ṣùgbọ́n ohun tí a ṣe ni pé a fi ẹnikàn ṣe Gómìnà fún wọn láàrin w, orúkọ ọkùnrin náà ni Àpáta-ìgbẹ̀yìn tí ó jẹ́ aládùúgbò Kùmọ̀dìran ní ìlé. A wí fún ún pé kí ó ṣe ìtọ́jú ìlú náà dáadáa àti wí pé àwa ó fi ibẹ̀ sílẹ̀ ní ìkáwọ́ rẹ̀ kí a lọ sí Igbó Elégbèje. Ìgba tí a bá ń padà bọ̀ a ní ìrètí pé ojú àwọn Èdìdàrẹ́ yóó ti là. Ìdí rẹ�� tí a fi fi Àpáta-ìgbẹ̀yìn ṣe Gómìnì ibẹ̀ ni pé òun jẹ́ ẹni líle, kò ní gba ìwọ̀sí fún àwọn Èdìdàrẹ́, nítorí wọn kò gba ojú bọ̀rọ̀. A tilẹ̀ ṣe ànìyàn pé kí Àpáta-ìgbẹ̀yìn ṣú Ìlábùrù ní opó, ṣùgbọ́n kò fẹ́, a wí títí, ṣùgbọ́n ó kọ̀ jálẹ̀ o ní kò wu òun, àti pẹ̀lú pé òòrùn ara rẹ̀ kòì tíì tán, nígbà tí ó kọjá lọ́dọ̀ òun o ń rùn sí òun. ẸBỌRA ÌGBÉRAGA-ÌBÁNÚJẸ́ ÀTI AHỌ́NDIWÚRÀ ÌYÀWÓ RẸ̀ A kúrò ní ìlú àwọn Èdìdàrẹ́ lẹ́yìn tí a ti gbé ibẹ̀ fún odidi oṣù mẹ́ta gbáko, a kọ orí sí ọ̀nà wa. Ẹ má jẹ́ kí èyí yà yín lẹ́nu pé a pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ bí ìlú kan tí a kò lọ sí ibi tí wọ́n rán wa. Ọba pàápàá tí fún wa ní àṣẹ bẹ́ẹ̀ kí á tó kúrò ní ilé, o ti wí fún wa pé bbí a bá dé ibikíbi tí a rí i pé ohun tí a f ẹ́ ṣe yóò gbà wá tó oṣù mẹ́fà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí a máṣe kánjú, kí a ṣe é dáadáa. Ìrìnàjò wa dára lẹ́yìn tí a kúrò ní ìlú àwọn Èdìdàrẹ́, a kò sì rí nǹkan kan títí a fi de inú igbó ńla’kan báyìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aginjù Babalórìṣà. Ìgbà tí a dé aginjù yíì ló tún di kí a máa rí àwọn iwin. N ó sọ nǹkan kan tí a rí ni òru ọjọ́ fún yín: ó ṣe ni, èmi tilẹ̀ sùn lọ, ni àwọn ènìyàn mi lú mi pẹ́pẹ́ láàrin òru tí wọ́n jí mi. Nígbà tí mo wò yíká, ilẹ̀ ti ṣú bámúbámú. Mo bèèrè ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi jí mi, wọ́n ní ki n fetí sílẹ̀ nítorí àwọn ń gbọ́ ohùn tí kò jọ ti ará ayé tí ó dàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rùn àwọn èrò ọjà ti wọn ń ho yànmù létí ẹni. Lóòótọ́ náà, mo fetí sílẹ̀ mo sì ń gbọ́ ohùn àwọn ẹranko inú igbó àti àwọn ejò inú aginjù, àwọn igi àti àwọn ọ̀pẹ̀, ewéko àti ìtàkùn, dúkìá gbogbo ti ń bẹ ní orí òké àti ohun àlùmọ́ọ́nì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, àwọn ẹja inú omi àti àwọn kòkòrò orí ilẹ̀- gbogbo wọn ń kígbe wọn ń wí báyìí pé, ‘Lọ! Lọ! Lọ! Jáde! Jáde! Má dúró tì wa, ma dúró ti wa, àwa kò fẹ́ ọ, àwa kò bá ọ ṣe àjọpín, Ìgbéraga, àbàwọ́n inú ayé, Ìgbéraga, ìfàsẹ́yìn ọmọ ènìyàn, Ìgbéraga, má kó tìrẹ ràn wá, máa lọ, máa lọ, máa lọ jọ̀wọ́ máa lọ o:-:-: jọ̀wọ́ máa lọ o:-:-:-: jọ̀wọ́ máa lọ o:-:-:-: Báyìí ni mo gbọ́, ṣùgbọ́n àyà mi kò já ju bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí láti ìgbà tí mo ti di olórí ni mo ti pinnu pé n kò ní bẹ̀rù mọ́, nítorí bí olórí ba ń bẹ̀rù jù, kò ni lè ṣe alákòóso àwọn ọmọ ẹ̀yìn, bí aṣáájú bá bá ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀, àwọn èrò ẹ̀yìn yóò sáré tágbára tagbára. Mo rọra díde lórí ibùnsùn mi, mó ń wo ibi ti mo ti n gbọ́ ariwo yìí. Nígbà tí o ṣe, mo rí ìmọ́lẹ̀ ǹlá kan tí kò yàtọ̀ sì òòrùn gangan tí o ràn yí ibi ribiti kan báyìí yípo, ẹnu ibi tí òòrùn èèmọ̀ yìí ràn sí to ẹsẹ̀ bàtà méjìlá ní ìbú ó sì tó bẹ́ẹ̀ ní gígùn, gbogbo ìyókù lẹ́yìn òòrùn birikiti yìí wà ní òkùnkùn biribiri. Nígbà tí mo wo ààrin ibi tí òòrùn yìí wà mo rí àwọn iwin méjì, ọ̀kan jẹ́ ọkùnrin èkejì sì jẹ́ obìnrin. Èyí ọkùnrin dé fìlà kan tí o fi ara jọ adé tí o ń kọ mọ̀nàmọ̀nà bí òkúta díámọ́ǹdì, ẹ̀wù rẹ̀ jẹ́ agbádá wọ́n sì gé onírúurú òkúta olówó iyebíye pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ wọ́n fi ṣe ọnà sí i lára, gbogbo ìwọ́nyí ń dán gbinringbinrin bí ìgbà tí alágbẹ̀dẹ pàtàkì bá ṣe ohun ọ̀ṣọ́ dídára fún gbajúmọ̀ obìnrin. Àti ṣòkòtò, àti ẹ̀wù, àti fìlà iwin yìí rí jìngbìnnì kanlẹ̀, bí o ba sí ti ń rìn, wọn ń dún jinwinjinwin bí ìgbà tí àwọn abọ̀rìsà ba n lu ìlù agogo ijó òríṣà wọn. Èyí obìnrin dára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, ó ró aṣọ ìlẹ̀kẹ̀ wẹẹrẹ kò sí ìyàtọ́ láàrin obìnrin yìí àti àwọn ọmọ aráyé bí ko ṣe ahọ́n rẹ̀ tí ó gùn láàrin rékọjá tí ó tayọ ẹnu tí ó sàn sí igbá àyà rẹ̀ títí ó fi kàn án ni ìdodo. Bí àwọn iwin méjì yìí ti ń súnmọ́ wa ni ìmọ́lẹ̀ ńlá náa ń bá wọn bọ̀ lọ́dọ̀ wa. Bí mo sì ti rii pé wọ́n n sunmọ wa, mo dìde dúró, mo ké ní ohùn rara, mo ni, ‘Àlááfìaà ni ẹ̀yin ń bá bọ̀ àbí kùmọ̀? Èyí ọkùnrin sì dá mi lóhùn, ó ni, ‘Àlaafìà ni.’ Ṣùgbọ́n mo sàkíyèsí pé bí wọn tí ń bọ̀ tí wọn n wọ aṣọ dídára to nì, ẹkún ni àwọn méjéèjì ń sun. Mo bá tún sọ̀rọ̀ mo ní, ki ni ìdí rẹ̀ ti ẹ fi ń sọkún nínú aṣọ jìngìnnì irú èyí? Lẹ́yìn náà ni iwin yìí bẹ̀rẹ̀ si ọ̀rọ̀ i sọ, ó ní; Èmi ni Ìgbéraga-ìbànújẹ́, ọmọ ìmọ́lẹ́ òun òkùnkùn, ti ń gbé ìpàdé ayé òun ọ̀run. Bàbá ni Ìmọ́lẹ̀ jẹ́ fún mi ṣùgbọ́n ìyá mi ni òkùnkùn. Ìyá mi ni mo jọ, n kò sì fi ibi kan jọ bàbá mi ni o sì mú u lójú ogun, lákòókò tí ìjà dé láàrin àwọn ara òde ọ̀run àti Èṣù, tí Èṣì dúrò gẹ́gẹ́ bí olórí ogun láti da ojú ìjà kọ Ọlọ́run ọba. Bàbá mi ń jà fún Olódùmarè, ṣùgbọ́n ìyá mi ni ìyálóde ti ń wa oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun Èṣù lákòóòkò ìjà náà. Ìjà náà pọ̀ gidigidi ṣùgbọ́n àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Olódùmarè ṣẹ́gun, èyi ló sì mú kí a lé Èṣù kúrò ní òde ọ̀rùn tí o fi di pé o ń gbé ọ̀run Àpáàdì di òní olónìí. Ní ọdún kẹẹdọ́gbọ̀n tí wọ́n bí mi ni mo fẹ́ wúndíá kan láti ìlú ìyá mi, òun ni ó sì dúró tì mi yìí, Ahọ́ndiwúrà ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́, òun sì ni àkọ́bí ọmọ tí Àjàkálẹ̀- àrùn bí fún Ikú ní ìlú ìyá mi. Ní ọjọ́ ìgbéyàwó wa, gọngọ sọ ni ìpàdé ayé òun ọ̀run. Jọ́ náà ni bàbá mi fún mi ní ẹ̀wù ìmọ́lẹ̀, ó wí pé: Ibikíbi tí ìwọ ba ń lọ, ìbáà ṣe ọ̀sán, ìbáà se òru, o kò ní rìn nínú òkùnkùn láéláé’(gbogbo àwọn màlékà sí dáhùn pé ‘Àmín’) Ìyá mi pẹ̀lú fún mi ni ẹ̀bùn, ó fún mi ni agbáda ńlá tí ìwọ rí lọ́rùn mi yìí, ìsàlẹ̀ àpótí Èṣù ní wọ́n sì ti mú u jáde, gbogbo àwọn ará òde ọ̀run a sì máa pé agbádá náà ni “Ẹ̀wù ìgbéraga” Òótọ́ náà sì ni, nítorí àti ọjọ́ tí ẹ̀wù yìí ti de ọrùn mi ni inú mi ko ti dùn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò lè bọ́ ọ, o di ọjọ́ tí mo bá rí ọmọ aráyé tí yóò rán mi lọ́wọ́ nípa rẹ̀. Èmi pàápàá mọ̀ pé láti ọjọ́ tí mo ti wọ ẹ̀wù náà ni mo ti di onígbéraga, nǹkan mi ni o máa ń dára lójú mi, mo ń hùwà bí ẹni pé ta ni máa mú mi, ìrin ṣeẹ̀ mi, ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ìṣe mi sí ẹnikẹ́ni, ti ìgbéraga ni. Ojoojúmọ́ láti ọjọ́ tí mo ti wọ ẹ̀wù yìí ni àwọn ẹbọra ọ̀run ń sẹ nǹkan tí kò dára ju tèmi, bẹ́ẹ̀ ni n kò fẹ́ kí nǹkan ẹnikẹ́ní gbé tèmi, eléyìí a sì máa bà mi nínú jẹ́, bí mo bá ti ń rí ìlọsíwájú wọn ni inú ń bí mi, èmi a sì máa sọkún títí lójóòjúmọ́ ọjọ́ ayé mi. Ìyàwó mi pẹ̀lú, ko yàtọ̀ sí mi jù bẹ́ẹ̀ lọ, bọ̀kìní òun ọlọ́rọ̀ ẹgbẹ́ra, ọ̀bún ùn asiwèrè ọ̀kanùn, ọ̀kańjúà òun olè, déédéé ni wọ́n já sí. Ní ọjọ́ ìgbéyàwó wa, Àjàkálẹ́-àrún tí í ṣe ìyá òun gba agbára lọ́wọ́ Èṣù, ó fa ahọ́n ìyàwó mi yọ. O sì fi òmíràn pààrọ̀ rẹ̀, eléyìí ni náa ni ahọ́n gbọọrọ tí ìwọ rí yìí, tí ó tayọ ẹnu tí ó sì gùn dé ìyàwó mi ní dodo. Kò sí obìnrin náà lode ayé tàbí lóde ọ̀run tí o lè ro ẹjọ́ ẹlẹ́jọ́ kiri to bi ìyàwó mi yìí, nítorí ahọ́n abàmì gígùn yìí a máa tìkararẹ̀ ro ẹjọ́ láìjẹ́ pé ìyàwó mi rán an, ahọ́n náà sì máa gbọ́ràn bí ènìyàn, ko sì si ibikíbi tí ẹnikẹ́ni ti lè sọ̀rọ̀ wa lónìí tí ahọ́n yìí kò níí sọ fún wa. Ọ̀rẹ́ tí kò jẹ́ ròyìn ẹni tí o sọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ òun ní rere àfi ẹni tí o bú u, irú àwọn báwọ̀n-ọnnì ni adíjàálẹ̀-takété, ọ̀bàyéjẹ́ ènìyàn. Ipo yìí ni ahọ́n èèmọ̀ yìí dúró sí fún ìyàwó mi, ahọ́n tí ó gbà lọ́wọ́ Àjàkálẹ́-àrùn ti i ṣe ìyàwọ mi, ahọ́n tí ó gbà lọ́wọ́ Àjàkálẹ́-àrùn ti i ṣe ìyàwọ Ikú lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa. Ẹlẹ́dàá fi ọmọ jínkí wa, abí ọmọ méjì, ọ̀kan ọkùnrin, ọkan ọbìnrin. Èyí ọkùnrin tí o jẹ́ àkọ́bí ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìṣubú. Orúkọ àbíkẹ́yìn tí ó jẹ́ obìnrin sì ni Ìparun. Àwọn méjéèjì ti gbéyàwó, ọmọbinrin tí Ìṣubú tilẹ̀ kọ́ fẹ́ ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ ìtìjúparẹ̀ tí ó jẹ́ ọmọ olórúkọ mi ni ọ̀rùn Àpáàdì, èyí ni pé bpabá rẹ̀ náà a máa jẹ́ Ìgbéraga Ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n nígbà tí a lọ tọrọ ọmọ náà ni wọ́n wí fún wa pé ìbátan wa ni ìyá rẹ̀ nítorí ilé kan náà ni wọ́n gbé bí Ahọ́ndiwúra tíí ṣe ìyàwo mi àti ìyàwó ọmọ náà. Nígbẹ̀yìn ṣa, Ìṣubú fẹ́ ọmọbìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìbànújẹ́-òde. Eléyìí nì náà bá wa tan díẹ̀, ṣùgbọ́n ìtàn gígùn ni, nítorí bàbá rẹ̀ ni Àìsán-fẹ̀yìntì tí ó jẹ́ ọmọ Àìmọ̀kan tí ó ba ìyá mi, Òkùnkùn tan. ọk��� Ìparun ni Jàgùdà páálí tí obìnrin kan báyìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀fẹ́-ilé bí fún Bìlísì. Lórí gbogbo èyí, ìwọ ọmọ ènìyàn, jọ̀wọ́ mo bẹ̀ ọ́ gidigidi bá mi bọ ẹ̀wù ìgbéraga ọrùn mi, nítorí kò jẹ́ kí inú mi dùn ráá. Kò sò jẹ́ kí inú Olódùmarè kò dùn sí mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí iní Olódùmarè kò dùn sí kan ìjàngbọ̀n. Ràn mi lọ́wọ́, jọ̀wọ́, ọmọ ènìyàn, bá mi bọ ẹ̀wù ìgbéraga. Báyìí ni iwin náà sọ, lẹ́yìn èyí mo wo ojú sánmọ̀ mo ra ọwọ́ sí òkè mo ke pe Ọlọrun ọba pé kí ó máṣe bínú sí mi pé mo fẹ́ ṣe oore fún iwin náà, kàkà bẹ́ẹ̀ kí ó kàá kún iṣẹ́ rere kan pàtàkì tí mo ṣe ni òde ayé, mo bá pe Ìgbéraga-ìbànújẹ́ kí ó súnmọ́ mi, lẹ́yìn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ mo wo ẹ̀wù náà bí ó ti ri, mo ríi, ó lẹ̀ mọ́ ọ lára típẹ́típẹ́, mo tilẹ̀ kọ́ ṣe bí ẹ̀wù náà lẹ̀ mọ́ ọ lára ni, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ irun ara iwin náà gùn púpọ̀ òun lo sì wé mọ ara ẹ̀wùi náà. Mo bá pe àwọn ènìyàn mi, mo ní kí olúkúlùkù mú abẹ nínú àpò rẹ̀ kí á gé ẹ̀wù náà wẹ́lẹwẹ̀lẹ kúrò lara iwin náà. Ìgbéraga-ìbànújẹ́ dùbúlẹ̀, bí ogójì ènìyàn bẹ̀rẹ̀ síi ṣiṣẹ́ sí ara ẹ̀wù rẹ tí a ge ẹ̀wù náà wẹ́lẹwẹ̀lẹ tí a fi bọ́ ọ kúrò lára rẹ̀ tán po. Ìgbà tí a ṣe eléyìí tán, inú iwin náà dùn púpọ̀, ṣùgbọ́n ó ku bí a o ti ṣe ahọ́n ìyàwó rẹ̀ gígùn gbọ̀ọ̀rọ̀. Ibi tí mo ti ń ronú eléyìí, ni mo rí omi tí ó kán sílẹ̀ lára ẹ̀wù Ìgbéraga-ìbànújẹ́, mo lọ sí ibi tí ẹ̀wù náà wà, nígbà tí mo sì fi ọwọ́ kan omi náà ó dàbí afárá oyin. Ṣùgbọ́n bí mo ti n ti ibi tí àkísà ẹ̀wù náà wà bọ̀, mo yà sí ọ̀dọ̀ Ahọ́ndíwúrà, mo fi ọwọ́ kan ahọ́n rẹ̀ gígùn, bí omi tí ń bẹ lọ́wọ́ mi sì ti kan ahọ́n náà ni mo ri i ti o n ká wọ inú bí ẹ̀wọ̀n agogo. N kò sì dúró pẹ́ títí tí mo ri i tí ahọ́n yìí sá wọlé tan tí ahọ́n mìíràn yọ dípò rẹ̀ tí ó ṣe ìwọ̀n ẹnu. Báyìí ni èmi àti àwọn ẹnìkéjì mi ṣe ìrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Ìgbéraga-ìdànújẹ́ ọmọ Ìmọ́lẹ̀ òun òkùnkùn, ti ń gbé ìpàdé ayé òun ọ̀run àti ìyàwó rẹ̀, Ahọ́ndiwúrà, tíì ṣe ìyá Ìṣubú àti Ìparun, ọmọ Àjàkálẹ́-àrùn òun Ikú, tí í ṣe ìyá ọkọ Ìbànújẹ́-òde. Nígbà tí ohun gbogbo parí tán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sẹ̀, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í mì, àrá ń sán, igbó n pariwo, àwọn igi àti ọ̀pẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í ké wí pé: Ẹ ṣeun, a dúpẹ́, a dúpẹ́, a dúpẹ́, ọ̀nà yín yóò dára, ilé yín yóò sunwọ̀n, ẹ ṣeun, A! Ẹ ṣeun, ẹ ṣeun abbl. Gbogbo ìwọ̀nyí sẹlẹ̀ lóru, ìgbà tí àwọn iwin méjì yìí dúpẹ́ lọ́wọ́ wa tí wọ́n lọ tán, àwa náà sun oorun díẹ̀ si i, kò sì pẹ́ lẹ́yìn èyí ilẹ̀ mọ́. Ìgbà tí ó tún di ọ̀sán ọjọ́ kejì ni nǹkan bí agogo méjìlá a tún rí nǹkan abàmì mìíràn. A FI OJÚ WA RÍ Ọ̀RUN ÀPÁÀDÌ B í a ti dé ibi kan tí ó dákẹ́ minimini báyìí, tí igbó ibẹ̀ dí tí o dúdú mírínmírín ni a rí iwin kan tí ó ń bọ̀, ó dàbí ọba gan-an, ìgbà tí a sì kọ́ rii, a ké “Kábíyèsí” ati gbàgbé pé aginju Babalórìṣà ni a wà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ibi tí ẹbọra náà fi yàtọ̀ sí ọba. Fìlà orí rẹ̀ dàbí adé, bàtá ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí bàtà ẹsẹ̀ àwọn alágbára, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀wù ọrùn rẹ̀ kò yàtọ̀ aí ti ọba tí ó ti gba adé láti ọwọ́ òdùduwà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iwin mìíràn ni ó tèlé e. Ìgbà tí gbogbo àwa ọdẹ dọ̀bálẹ̀ tí a kí iwin pàtàkì yìí, ó dáhùn ó ni, “Ibo lẹ̀ ń lọ báwọ̀nyí ẹ̀yín ọmọ ènìyàn?” Emi náà fèsì mo ní, ‘Kábíyèsí’, à ń lọ sí òkè Ìrònú ti ń bẹ nínú Igbó Elégbèjè, kí ọgbọ́n bà túbọ̀ wọ inú [[ilú wa, kí òye ba túbọ̀ wọ ibẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi bẹ̀ yín tọkàntọkàn, ẹ má sàì sọ ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, ẹ ma sì sàì sa ipá yín fún wa lọ́nàkọnà tí ẹ bá mọ̀ tí o lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún wa. Nígbà tí iwin náà gbọ́ báyìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ó ní: Èmi ni Adéforítì, ẹbọra tí ilé rẹ̀ ń bẹ lájùlé ọrun, orúkọ tí Olódùmarè fún mi ni èyí, nítorí emi ni ó ní ìforítì jùlọ láàrin ẹ̀dá. ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan rere gbogbo sì ni ìforítì tì mú bá mi. Ẹ̀dá tí kò bá ní ìforítì, yálà nínú ayé ni tàbí lóde ọ̀run, ẹ̀dá lásán ni. Ní [[akókò tí iwin burúkú kan ni etí òde ọrun bá ọmọ rẹ̀ jà, tí kò sí ẹni tí ó lè la ìjà náà, èmi ni mo parí ìjà wọn. Orúkọ iwin burúkú yìí ni Ìbínú-ẹkùn tíí ṣe ìbátan Ìgbéraga-Ìbànújẹ́ ní ìdí ìya Ìbínú-ẹkùn ni ẹni tí ó lè bínú jùlọ láàrin ohun gbogbo ti ń bẹ lójú omi tàbí ní ìsàlẹ́ ilẹ̀, tí ó wà lófuurufú tàbí ní ìyàngbẹ ilẹ̀. Ní àkókò ìjà yìí, gbogbo àwọn ẹbọra òde ọ̀run bẹ̀ẹ́, ṣùgbọ́n òun kò gbọ́, ó lé ọmọ rẹ̀ wá sínú ayé kí ó bà lè ní ìpín nínú ìbànújẹ́ ti n tẹ̀lẹ́ ọmọ ènìyàn kiri títí ọjọ́ ayé wọn. Mo dìde mo lọ sílé Ìbínú-ẹkùn láti yíì lọ́kàn padà kúrò nínú èrò yìí, ṣùgbọ́n pẹ́lú kùmọ̀ ni o fi lé mi jáde. Ni ọjọ́ kejì, mo tún lọ, ṣùgbọ́n bí ó ti fi ojú kàn mi ni ó yìnbọn, díẹ̀ ló sì kù kí ìbọn náà bá mi. Mo tún lọ ní ọjọ́ kẹta pẹ́lú, ṣùgbọ́n ó bú mi láti ẹsẹ̀ mi dé orí koko, ó fa àdá yọ, ní ìgbẹ̀yìn ó fi àdá lé mi dé ilé mi koko. Síbẹ̀ mo lọ ni ọjọ́ kẹrín, ṣùgbọ́n ó fi ogede pe ajá eṣù láti ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ni inú òkùnkùn biribiri kí ajá náà bà wá pa mi jẹ, ṣùgbọ́n ọwọ́ ajá náà kò tẹ̀ mi, mo sì tún mu sùurù mo lọ ba Ìbínú-ẹkùn ní ọjọ́ kàárún, ṣùgbọ́n ki n tó dé ọ̀hún o ti mọ̀ pé mo ń bọ̀ o sì ti kó onírúurú ẹ̀dá ọ̀run tí ìwà wọn bá tirẹ̀ mu sílẹ̀ dè mi, bí mo ti yọ lọ́kàn-án kán ni mo rí gbogbo wọn pẹ̀lú ohun ìjà tí i wọ́n fẹ fi ṣe mi ni ìjàǹbá, ṣùgbọ́n èmi dúró lókéèrè mo sì bẹ Ìbínú-ẹkùn tàánútàánú pé kí ó ṣe àforíjì fún ọmọ rẹ̀, lẹ́yìn èyí nì èmi náà padà lọ sí ilé mi ṣùgbọ́n bí ilẹ̀ ọjọ́ keeje ti ń mọ́ hàì ni mo tún dide, mo bá ilé Ì ínú-ẹkùn lọ, àṣé òun ti ní èrò pé mo lè wá bá òun o sì ti dẹ pàkúté sí ọ̀nà dè mi ni òru. Rírí tí ó rí mi ni inú bí i tí o ń sáré bọ̀ wá pàdé mi. O gbàgbé pé òun ti dẹ pàkúté sí ojú ọ̀nà dè mí, ibi tí o ti ní kí òun kọjá ní ojú ọ̀nà wá bá mi ni pàkúté mú u, ọ̀ràn mi wa túbọ̀ lẹ, ìjàngbọ̀n ń le mi bọ̀ mo pàdé ìjàngbọ̀n lọ́nà àti kúrò lọ́wọ́ ìjàngbọ̀n di ìjàngbọ̀n fún mi. Mo yára bẹ àwọn ìwin ti ń bẹ lágbègbè ibẹ̀ kí wọ́n bá mi tú Ìbínú-ẹkùn sílẹ̀, kí wọ́n sì tó ṣe è’yi tán, mo ki iré malẹ̀ mo sáré tagbáratagbára. Ìgbà tí wọ́n tú u sílẹ̀ tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá mi kiri, ó ránṣẹ́ lọ sílé ayé, ó rán lọ sí àjùlé ọ̀run ó wá mi dé ọ̀run àpáàdì pàápàá, ṣùgbọ́n kò rí mi mo fi ara pamọ́ pátápátá nítorí mo tí mọ̀ pé mo dá ọ̀ràn tí ó kọjá ọ̀ràn, mo wo kìnìún lójú, mo ṣe ‘síọ̀’sí ìjàpá, mo tẹ ọká ní ìrù mọ́lẹ̀, mo mú obìnrin jáde lọ́jọ́ tí orò gba ojúde. Nítorí ẹ̀sẹ̀ mi ńlá nì, mo ba inú ihò ìlẹ̀ lọ. ọgọ́ta ọjọ́ ni mo sì ṣe ki n tó jáde. Ní òpin ọgọ́ta ọjọ́, mo jáde. Jíjáde tí mo sì tún jáde pẹ̀lú, ilé Ìbínú-ẹkùn ni mo kọ orí sí. Àkókò yíì gan-an ni olórí-burúkú yìí wá mú mi, ó lé mi ó bá mi nibi tí mo ti ń sálọ. Nígbà tí o sì mú mi, o fi okùn sí mi ni ẹsẹ̀ o sì so mi mọ igi rẹ̀gẹ̀jì kan ti ń bẹ ní ìta rẹ̀, mo kọ orí sí odò mo ń fi dírọ̀dírọ̀, o sì gbé ẹrù pàsán jáde, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fà wọ́n yọ lọ́kọ́ọ̀kan o sì ń nà mi. Nígbà tí ó ṣe tí mo rí jọ̀wọ̀lọ̀ tí mo sì ń kú lọ. O tíí ẹsẹ mi kúrò lára igi o sì gbé mi jù sílẹ̀ ó ṣebí mo ti kú ni. Lẹ́yìn èyí ó wọ àgbàlá rẹ̀ lọ o sì bẹ̀rẹ̀ síí wá igi láti ffi dáná sun mi, ṣùgbọ́n kí ó tó padà dé, atẹ́gùn ti fẹ́ sí mi mo sì ti dìde, mo sálọ. Ìgbà tí mo dé ilé mi, mo ṣe ìtọ́jú ara mi dáadáa, kí ilẹ̀ sì tó mọ́, ara mi ti le. Mo tún dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó di ilé Ìbínú ẹkùn. Ìgbà tí mo yọ lọ́kàn-án kán, tí ó rí mi, agara ti dá a, o ju ọwọ́ sí mi pé kí n máa bọ̀, èmi náà sì lọ, mo wọ inú ilé rẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù ṣùgbọ́n láìpẹ́ ni mo rí i pé èrè ìforítí mi ti dé, mo ti ṣẹ́gun, mo ti gun òkè dé orí, mo ti ṣe dáadáa nínú ìdánwò, mo ṣẹ́gun Ìbínú-ẹkùn pátápátá, ojú rẹ̀ rọ̀, mo pe ọmọ rẹ̀ wọlé, o túúbá níwájú baba rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni mo paríu ìjà líle náà. Gbogbo bí mo ti ń ṣe ni Olódùmarè ń wò mi, ìgbà ttí mo sì n padà bọ̀ wá sí ilé, mo gbọ́ ohùn kan láti òkè wí pé, ‘Nítorí ìwọ ṣe èyí a ki yóò pè ọ ni orúkọ àtijọ́ mọ́, Adéforítì la ó máa pè ọ, nítorí ìwọ ní ìforítì ju àwọn ẹ̀dá ìyókù lọ.’ Àti ọjọ́ yìí wa ni Ẹlẹ́dàá ti ohun gbogbo tẹ́ mi lọ́rùn ní ilé mi, ṣùgbọ́n ìwọ ọmọ ènìyàn bí mo ti ri ọ lónìí inú mi dùn jọjọ, mo sì fẹ́ kí o wí fún àwọn ènìyàn rẹ kí ẹ tẹ̀lé mi kí ẹ wa lọ̀ mọ ilé mi. Nígbà tí ó wí báyìí tán mo tọrọ ààyè lọ́wọ́ rẹ̀, kí ó fún mi ní ààyè díẹ̀ kí èmi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi lọ ronú nípa ọ̀ràn náà, ó sì gbà bẹ́ẹ̀ fún mi. Nígbà tí a bìlà sẹ́yìn díẹ̀ báyìí tí a jókòó ní ibi kan tí a ṣe àsàrò lórí ọ̀ran náà, ogunlọ́gọ̀ nínú àwọn ọdẹ ni wọ́n fẹ́ pé kí a bá a lọ. A bá tẹ̀lé e. A kò rrìn tó bẹ́ẹ̀ nígbà tí ó déédéé dúró tí o bá ilẹ̀ sọ̀rọ̀ ó ni, ‘Ìwọ ilẹ̀, la ẹnu fún mi, mo fẹ́ lọ sí ilé ìyá mi.’ Bí ó ti wí báyìí, pẹ̀rẹ́ ni ilẹ̀ là tí a sì rí àtẹ̀gùn dídára ka báyìí tí ó ba ihò ilẹ̀ lọ, gbogbo wa sá bẹ̀rẹ̀ síí tọ àtẹ̀gùn yìí bá ìsàlẹ̀ lọ. Ìgbà tí a dé ọ̀hùn, a bá ara wa nínú ààfin ńlá kan tí ó dára tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ọ̀rọ̀ láti fi sàpèjúwe ibẹ̀, àṣé ilé rẹ̀ ni èyí nì. Ìgbà tí a dé ọ̀hún, o mú wa tọ ìyá rẹ̀ lọ, o fi wa hàn án, ìyá rẹ̀ náà sì kí wa dáadáa, ìyá rẹ̀ náà sanra díẹ̀ gbogbo ara rẹ̀ si ń dán, ó mọ́ tónítóní ṣùgbọ́n ojú rẹ̀ kò dàbí ojú ènìyàn nítorí ṣe lo ri rubutu b’’i ojú igbá tàbí ojú ife ẹmu, ojú méjì ni ṣe ni àwọn ojú méjì náà sì ń yí sókè sódò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ́kan, ó ba ni lẹ́rùn gidigidi. Ṣùgbọ́n eyín rẹ̀ funfun ti n kò rí irú rẹ̀ rí, ó dára ó rí wẹẹrẹ. Lẹ́yìn tí a kí ìyá rẹ̀ tán, ó mú wa lọ sí ibi tí a máa gbé, ó ní kí á dá ara wa sí ọ̀nà mẹ́rin, a sì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n bákan náà ni gbogbo iyààrá ńlá ńlá náà rí. Lọ́jọ́ tí mo ti dé inú ayé n ò gbádùn tó bí mmo ṣe gbádùn nínú ilé iwin yìí rí. nítorí pé ohunkohun tí a bá fẹ́ ń bọ̀ síwájú wa ni, kò sí pé à ń bèèrè lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, kí a tó rii. Bí a bá wí pé iṣu ń wù wa jẹ, wéré ni iṣu a bọ́ sílẹ̀ níwájú wa tí yóò maa hooru nínú àwo, bí a bá wí pé ìrẹsì ń wù wá jẹ òun ọbẹ̀ adìẹ̀, kí á wo iwájú kí a rí ìrẹsì àti adìẹ tí wọn ti dín tí ó gbẹ tẹ́kítẹ́kí ni. Ìgbà kan tí mo wí pé ẹmu ń wù mi mu wéré ni mo rí ẹmu ògidi níwájú tí ó ru pàtà. Kò sí pé à ń wa nǹkan, a kò rí rárá. Nígbà tí ó di alẹ́ ọjọ́ tí a dé ibẹ̀ yìí, iwin náà wí fún ni pé oùn ní iṣẹ́ kan láti ṣe àti pé oùn sì fẹ́ kí a ran òun lọ́wọ́ láti ṣe nínú iṣẹ náà. Ìgbà tí a béèrè isẹ́ tí a fẹ́ ṣe yìí, o ní òun fẹ́ kọ́ ilé ‘Ìgbéga-ọ̀run’. Ilé yìí jẹ́ ilé Ẹlẹ́dàá ti ń fẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ará òde ọ̀run kọ́ àti pé nítorí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti gbìyànjú tí wọn kò lè kọ́ ọ o òun ti sọ fún Olódùmarè pé òun fẹ́ kọ́ ilé náà Olódùmarè sì gbà fún òun o sì ti fi ilẹ̀ ibi ti òun lè kọ́ ilé náà sí han òun, nítorí náà òun fẹ́ lọ bẹ̀rẹ̀ síi máa ṣánko kí òun ṣe díẹ̀ nínú iṣẹ́ náà lówùúrọ ọjọ́ kejì, inú òun ó sì dùn bbí a bá lè bá òun ṣan díẹ̀ nínú oko yìí. A gbà pé a ó ba a ṣíṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n gbé àpótí kan jáde, àpóti ti mo sọ pé mo rí pẹ̀lú wọn lójú ọ̀nà ni. Ìgbà tí wọ́n sì ṣí àpótí yìí wọ́n kó ẹ̀wù púpọ̀ jádè ẹ̀wù iṣẹ́ ni, wọ́n sì pin in fún gbogbo wa. Lẹ́yìn èyí, wọ́n kó àdá fún wa, a múra ó di inú igbó tí Ẹlẹ́dàá pa láṣẹ́ pé kí Adéforítì fi kọ ilẹ̀ ìgbéga-ọ̀run. A ṣán igbó gbogbo tí ó wà ní ibi tí a o kọ́ ilé Ìgbéga-ọ̀run sí, a padà wá sí ibi ti à ń gbé. Nígbà tí a o fi dé ìbẹ̀ ní ọjọ́ kejì, gbogb igbó wọ̀n-ọnnì ti dìde wọ́n dúró ṣánṣán, igi ti gbòǹgbò rẹ̀ ti hu tún rí gboǹgbò mọ́lẹ̀, ewé tí ó já sílẹ̀ tún padà lọ sí orí igi, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹka gbogbo padà lọ sí ibi tí wọn ti wà rí. a tún múra, à ń bá iṣẹ́ náà lọ. A parí oko yìí kí ilẹ̀ tó ṣú, a sì fa gbòǹgbò àwọn igi àti ìtàkùn tu, a dá iná ti igi ìrókò tí ó wà níbẹ̀ ní ọrùn, a wú gbòǹgbò awùsá, a sì to igi gbígbẹ yí ọ̀gànwò ká, a dá iná ńlá yí àwọn igi burúkú wọ̀n-ọnnì po. Eléyìí ni a ṣe tí a padà wá sí ilé. ‘Kùtù hàì òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ni a tún lọ bẹ ibẹ̀ wò. Nígbà tí a sò máa dé ọ̀hún, àwọn ewéko wọ̀n-ọnnì ti hù, iná tí a dá ti kú, ohun gbogbo tún ti pada di bí ti àtẹ̀yìnwá. Lẹ́yìn èyí, a bẹ̀rẹ̀ sii wa àwọn lébìrà kiri, àwọn ará ọ̀run gan-an, Adéforítì ni òun rò pé afi àwọn ará ọ̀run gan-an ni yóò lè bá òun ṣiṣẹ́ náà. Ó wá lébìrà títí kò rí, ó bá lọ sọ fún ìyá rẹ̀, ó ni, ‘Ìwọ ìyá mi tòótọ́, mo ti gbìyànjú bí ó ti yẹ ki ń gbìyànjú tó ṣùgbọ́n síbẹ̀ síbẹ̀ n kò lè ṣán oko tí ó wà nibi tí n o kọ́ ilé Ìgbéga-ọ̀run sí, ẹ ma bínú pé mo gbàgbé ki n sọ fún yin ki ń tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ìyá mi ọ̀nà wo ni mo lè gbà rí lébìrà tí yóò bá mi ṣiṣẹ́ náà ti n o fi lè kọ́ ilé ‘Ìgbéga-ọ̀run’? Ìyá rẹ̀ wò ó tàánútàánú nínú ilé wọn, ojú obìnrin náà yí sókè sódò o ń kọ bí mọ̀nàmọ́ná ojú ọ̀run, ó dáhùn ó ní, ‘Ọmọ mi, ọmọ mi, máṣe dáwọ́lé àti kọ́ ilé Ìgbéga-ọ̀run, àwọn tí ó jù ọ́ lọ ti gbìyànjú bẹ́ẹ̀ ni wọn kò le ṣee, nítorí Ọlarun ọba níkan ló mọ̀ bí ilé Ìgbéga-ọ̀run yóò ti ṣe di kíkọ́ ṣùgbọ́n nípa ti lébìrà, àwọn wọ̀n-ọnnì kò sí ni ìhín, wọ́n wà ní ọ̀run àpáàdì. Afi bí o bá lọ sí ọ̀run àpáàdì nìkan ni ó tó lè rí wọn. Bí o bá máa lọ, o níláti lọ gbé apo àlàáfíà ti ń bẹ ní iyààrá mi kí o fi pa ara, nítorí kí iná ọ̀run àpáàdì má ba le ṣe ọ ní nǹkankan, bí o bá sì fẹ́ mú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lọ, àwọn ènìyàn wọ̀nyí, o níláti fún olúkúlùkù wọn ní fìlà àírí ti ń bẹ nínú àpótí ńlá ní àbáwọ inú iyààrá mi kékeré, kí wọ́n dé e nítorí Èṣù kò gbọdọ̀ rí wọn, ṣùgbọ́n bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnikẹ́ni kò ni lè rí wọn bí kò ṣe ìwọ, síbẹ̀ àwọn náà níláti fi epo àlááfíà pa ara. Bí o bá pinnu láti lọ dandan (nítorí mo wòye pé ọ̀ràn náà wà lọ́kàn rẹ púpọ̀). Ìgbà tí o bá dé ọ̀run Àpáàdì gan-na, máa lọ gan-an ran sí ọ̀dọ̀ Èṣù ní inú ààfin rẹ̀. Ṣùgbọ́n máṣe dọ̀bálẹ̀ fún-un, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ ké ‘Kábíyèsí’ nítorí ọjọ́ tí ọmọ ìmọ́lẹ̀ bá tẹríba fún Èṣù ni ayé ọmọ náà pín. Ìba ohun tí mo lè sọ fún ọ ni èyí, ọmọ mi’. Adéfirítì múra àtí lọ wa lébìrà dandan ó sì wí fún wa kí a múra di ọjọ́ kejì kí a ba òun lọ kí àwa náà tilẹ̀ wo bí ọ̀run Àpáàdì ti rí. Ìgbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, ó gbé ìgo epo àlááfíà jáde, gbogbo wa fi ra ara, lẹ́yìn náà ó pín fìlà àìrí fún ni, a dée ẹnikẹ́ni ko sì lè rí wa mọ́ àfi òun. Ẹ máṣe gbàgbé pe Àjùlé ọ̀run ni àwa wà yìí o, nítorí ibẹ̀ ni ilé Adéforítì. Ìgbà tí a míra báyìí tán, a múra ó di ọ̀nà ọ̀run Àpáàdì. Bí a ti kúrò ni àjùlé ọ̀run tán tí a fi àgbègbè ibẹ̀ sílẹ̀ pátápátá tí a fi ẹsẹ̀ lé ọ̀nà ọ̀run Àpáàdì, nǹkan tí ó kọ́ yà mì lẹ́nu ni ẹbọ tí ó wà ni ojú ọ̀nà ní apá ọ̀tún àti apá òsì lọ, ogunlọ́gọ̀ wà nínú àpáàdì tí wọ́n ń bu epo sí, ìgbà mìíràn odidi màlúù wọ́n a kó ẹyọ owo sí inú àpáàdì wọ́n á bu epo sii, wọ́n a la ìfub adìyẹ wọ́n á rọ epo sii. Gbogbo ẹbọ tí ọmọ aráyé n rú sí Èṣù ní ìkoríta wọ̀n-ọnnì, èyí tí wọ́n ba rú lójóojúmọ́ a wà ní etí ọ̀nà ilé Èṣù lọ, ìgbà tí Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá sì fi máa jẹ ti ọjọ́ kan tán, ọmọ aráyé á ti pèsè ti ọjọ́ kejì sílẹ̀, nítorí èyí, àpáàdì pẹ̀lú egungun ẹran a dàbi okiti ọ̀gán sí apá ọtun àti apá òsì ọ̀nà lọ, nítorí ọjọ ti pẹ́ tí àwọn ọmọ aráyé ti ń ṣe wọ̀nyí àpáàdì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé nígbà mìíràn tí ènìyàn bá wo tó apá ọ̀tún a rí egungun àti àpáàdì lọ ni ogunlọ́gọ̀ mẹ́ẹ̀lì, bí ó tún wo òsì a ri i bákan náà lọ. Ìgbà tí ó ṣe sá, a dé ọ̀run Àpáàdì ní ibi tí Èṣù ti ń ṣe ọba wọn. Nǹkan kín-ín-ní tí o lè kọ́ yà ẹnikẹ́ni lẹ́nu nígbà tí ó bá dé ọ̀run Àpáàdì ni àti sí èyò rárá fún ohunkóhun. Gbogbo ibẹ̀ rí ṣúkuṣùku ṣùkuṣuù, kò sí ọ̀nà kan tí ó gún gbogbo ọ̀nà rí wọ́gọwọ̀gọ. Lẹ́yìn náà, àti Èṣù àti àwọn ọmọ ogun Èṣù, kò sí èyí tí inú rẹ dùn rárá nínú wọn, ṣe ni gbogbo wọn fajúro. Èṣù kò rí àwa, ṣùgbọ́n àwa ríi dáadáa. Nígbà tí Adéforítì yọ sii ní ààfin rẹ̀, ṣe ni Èṣù ta gìrì bí o sì ti ń mu u kiri ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ rárá, bí igi kan bá dá, ayà èṣù á já, bí ẹnìkan bá fi ẹsẹ̀ kọ, àyà Èṣù ń là gààrà, ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ rárá, hílà hílo ni Èṣù ń bá kiri. Eléyìí hàn gbangba lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú, tó bẹ́ẹ̀ tí Adéforítì fi bi Èṣù wò ìdì rẹ̀ tí ọkàn gbogbo wọn ko fi balẹ̀ bẹ́ẹ̀. Èṣù dáhùn Èṣù wí pé: Àwa tí ó jẹ́ pé iṣẹ ibi ni iṣẹ́ wa mọ̀ pé ẹ̀san ń bọ̀ lọ́jọ́ kan, ṣùgbọ́n a kò mọ wákàtí náà tí ẹ̀san ó dé. A bá Èṣù lórí ìtẹ́. Ẹ̀dá tí ó ba ni lẹ́rù gbáà ni, ó ní ìwo kan ṣoṣo lórí, iní sì ń jò lára ìwo náà bẹ́ẹ̀ ni ìwo pàápàá kò jóná, ó ní ìyẹ́ méjì kùọ̀kùọ̀ kan báyìí ní apá, èékan rẹ̀ sì gùn, ó dàbí èékán àwòdì, eyìn ẹnu rẹ̀ pupa ó dàbí ẹ̀jẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ló wà lẹ́nu rẹ̀ tí ó ddúró bí itọ́ ẹnu, eyín wọ̀n-ọnní gbòòrò ọ̀kọ̀ọ̀kan to eyín mẹ́ta papọ̀ ṣe ọ̀kan ṣoṣo, gbogbo eyín náà sì mú bérébéré bí abẹ ìfárí. Ẹsẹ̀ Èṣù dàbí ẹsẹ̀ ògòǹgò, síbẹ̀, ó ṣebi ọba, nítorí ẹ̀wù tí ó wọ̀ sọ̀rùn, ti góòlù ni, ṣùgbọ́n góòlù náà ti dípẹtà èérí dúdú dúdú gbogbo ti bò ó, kò dán bi góòlù mọ́ bẹ́ẹ̀ ni góòlù ni. Ìgbà tí Adéforítì bá a sọ̀rọ̀ nípa lébìrà tí ó bá lọ fún un tán, Èṣù ṣe ìlérí àti fún un ní léebìrà ṣùgbọ́n ó wí fún adéforítì pé òun fẹ́ fi díẹ̀ hàn án ní ọ̀run àpáàdì kí ó tó lọ. Èṣù dìde, Adéforítì náà tẹ̀lé e, àwa náà tẹ̀lé wọn. Ìgbà tí a rìn díẹ̀ ni Èṣù wí pe: Adéforítì, ibi tí mo fẹ́ kọ́ mu ọ lọ ni ibi tí à ń pè ni “Pàkúté Èṣù” ibẹ̀ wà láti máa ran mi létí àti ṣe ibi ki n má ba gbàgbé. Ìgbà tí a de “pàkúté Èṣù” yìí nǹkan tí ó kọ́ fi hàn án ni owó góòlù tí ó pọ̀ tí ó pupa dẹ̀dẹ̀ tí o ń dán yinrinyinrin. Wọ́n kó owó náà sínú ibi kan báyìí tí ó dábí ilé tí ènìyàn kàn fún ẹyẹ. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ejò náà ni a o ri ejò ọká tí ó ká jọ tí ó gb’’e ẹnu sókè hanha. Èṣù tọ́ka sí i ó wí pé ‘Ìgbà tí mo ba wa sí ayé tí mo ti ọmọ ènìyàn mu owó wó, owó tí kì í ṣe tíwọn, wọn kò ń mọ̀ pé ejò ọka ni àwọn ti ọwọ́ bọ̀ lẹ́nu. Lẹ́yìn èyí, ó tún fi ilé kan han Adéforítì, a rí obìnrin àti ọkùnrin kan nínú ilé náà a sì rí ọmọ owú kan ní ilẹ̀. Ìgbà tí Èṣù dé ibẹ̀ ó ní, “Ẹ bẹ̀rẹ̀ kẹ” bí ó ti wí báyìí tán, ṣe ni ọkùnrin ki ọmọ owú mólẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ si í fẹ́ ọ mọ obìnrin lórí, lẹ́yìn èyí, Èṣù ní, Wòó bí ọkùnrin náà ti ń fọ irin mọ́ obìnrin lórí, bẹ́ẹ̀ ni tọkọtaya ni wọ́n? A tún kúrò ni ibi èyí o di ilé mìíràn, ìgbà tí a dé ọ̀hún, a rí àwọn ọkùnrin méjì lórí àkàsọ̀ kan, nígbà tí Èṣù dé ibẹ̀ ó wí fún èyí tí ó wà ni ìsàlẹ̀ àkàsọ̀ kí ó fa ẹsẹ̀ èyí tí ó wà lókè, lóòótọ́ èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ṣe bí ó ti wí, ó fà á lulẹ̀ wéréwéré, ó gba ipò rẹ. Bí o ti jókòó ní ipò tọ̀ún tán àfi riri tí a rí ejò ńlá kan tí o ń yọ orí bọ̀, tí ó lọ mọ́ ọkùnrin yìí, wéré ó pa á wéré ó gbé e mì. Bí ó ti gbé e mì tán Èṣù dáhùn ó ní, ‘o fi èrú gba ìbùkún, kò dúró gbádùn ìbùkún’. A ba tún ń lọ, kò pẹ́ púpọ̀ a dé ilé mìíràn a rí obìnrin arẹwà kan tí ó dára púpọ̀ a sì rí ọkùnrin kan tí ó dúró titi, bí a ti dé ibẹ̀ Èṣù dáhùn ó ni, ‘Ṣiṣẹ́ rẹ ki n rí ọ’ bi o ti wi báyìí, ṣe ni a rí obìnrin náà tí ó rẹ́rìn-ín sí ọkùnrin náà tí ó dúró, ó ni, ko sí ọkùnrin náà láyé tí ó dára tó ọ, kò sì sí ẹni náà tí mo fẹ́ràn tó ọ lóde ayé títí dé ara ìyá àti bàbá mi, fi ẹnu kò mi lẹ́nu, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n jùlọ.’ Bí ó ti wí bàyìí tí ọkùnrin yìí fi ẹnu kò ó ní ẹnu, kò jẹ́ kí ọkùnrin náà gbé orí kúrò lẹ́nu mọ́, o dì mọ́ ọ, o ń fà á lọ ó sì fà á dé ibi odò jíjìn kan, o fàá jù sínú odò, odò gbé onitọ́hùn lọ. Èṣù tún sọ̀rọ̀ ó ni, ‘kò mọ̀ pé ìfẹ́ ojú ló ní sí òun, ó fi ara sílẹ̀ ó jẹ́ kí ó fà òun sínú odò. Ìgbà tí a tún dé ibi kan a ri àwọn ọkùnrin mẹ́rin, ìgbà tí Èṣù dé ibẹ̀ o ní, ‘ẹ ṣe bi ẹ tíí ṣe,’ bí ó ti wí báyìí àwọn méta mú ẹni kẹrin ti wọ́n kó ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn tí wọ́n fún un lókùn danin-danin. Lẹ́yìn náà wọ́n kó ohun ìní rẹ̀. Ìgbá tí wọ́n tún ronú títí wọ́n kúkú pa a. Kò pẹ́ tí wọ́n pa á tán tí àwọn ẹnìkan dé tí wọ́n mú wọn lọ. Kò sì pé tí a rí i tá wọ́n yẹgi mọ́ àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta. Ó pẹ́ díẹ̀ ni a tún rí àwọn mẹ́ta yìí tí àwọn mẹ́ta yìí tí àwọn jáde níbòmìíràn láti inú iyààrá kan ó sì ya ni lẹ́nu pé ẹni tí o ti kú tún dide, ṣùgbọ́n àti ìgbà tí a rí i tí ẹnìkan tún mú wọn tí ó sọ wọ́n sínú epo gbígbóná, lẹ́yìn èyí, Èṣù wí pé : wò ó àwọn ọlọ́sà jí owó olówó wọ́n yẹgi fún wọn nínú ayé, ìgbà tí wọ́n tún dé ọ̀dọ̀ mi mo sọ wọ́n sínú epo gbígbóná.’Èṣù bá rẹ́rìn-ín díẹ̀ báyìí, èyí sì ni ìgbà kín-ín-ín tí a rí ẹ̀rín ní ẹnu rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni a tún rí ní pàkúté Èṣù ní ọ̀run Àpáàdì ṣùgbọ́n kò sí àyè láti to gbogbo wọn lẹ́sẹẹsẹ. Èṣù tún mu adéforítì lọ sí ibi tí ó pè ni òpópó Ìyà-ẹ̀sẹ̀. Ibi yìí ni wọn ti ń fi ìyà jẹ gbogbo ẹni tí o tí ṣe ibi nínú ayé kí wọ́n tó fi àyé sílẹ̀ ṣùgbọ́n èyí tí ó burú jùlọ́ ni pé wọn kò tún lè kú mọ́, kí wọ́n máa jìyà títí ṣá ni, Ẹni tí a kọ́ rí ya ni lẹ́nu púpọ̀, ìránṣẹ́ èṣù kan ló jókòó ti ọkùnrin náà ti o ń gbá ìṣó mọ́ ọ lójú tí onítọ̀hún ńn ké ṣa. Ẹnu ya Adéforítì púpọ̀, ṣùgbọ́n Èṣù wí fún un kí ó maṣe jẹ kí ẹnu ya oun kí o má sì ṣe káàánú rẹ̀, Èṣù ni, o kò mọ̀ bí ọmọ aráyé ti le tó ni, ẹni tí ìwọ́ ń wo yìí ti yọ ojú ẹni mẹ́fà lóde ayé, ó ti pàṣẹ kí wọ́n yọ èékán ọmọ ìka ṣẹ̀ mẹ́wẹ́ẹ̀wá ẹni mẹ́fà láàyè láìjẹ́ pé wọ́n ti kú, kò ha yẹ kí òun náà jìyà díẹ̀ ni? A tún rí ẹnìkan tí ó wà nínú ìkòkò irin, ìkòkò náà gbóná tó bẹ́ẹ̀ ti ó jẹ́ pé gbogbo ara rẹ̀ ló pupa dẹ̀dẹ̀, gbogbo ara ọkùnrin náà bó bòròkòtò ó ń ké, ‘Ara ń ta mi o, ara n ta mi o, ara ń ta mi o’. Àánú rẹ̀ ṣe ni ṣùgbọ́n Èṣù ko tilẹ̀ sọ pé òun gbọ́ nǹkan tí ó ń sọ, o wí fún Adéforítì pe ẹni tí o ri yìí ti rán àwọ̀ ẹranko mọ́ ènìyàn lára lóde ayé ó sì ti fa ẹni náà fún kìnìhún pa jẹ, o ti gbé ènìyàn sínú pósí láàyè, ó sì ti ní kí wọ́n so okún mọ́ ẹnìkan lápá àti lẹ́sẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ès]u méjì fà á, wọ́n ń fi í ra iná ìléru tí ó tóbi tí o ń jo tí ó gba gbogbo àgbègbè ibẹ̀ lọ, ọkùnrin yìí ń ké ṣùgbọ́n wọn kò fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò kú. Àwọn mìíràn wà tí wọ́n ti fa apá wọn kan ya kúrò lára wọn ti wọn ń gbé kùkùté tí ó kù kiri ti ẹ̀jẹ̀ wà bálabàla lójú apá tí wọ́n faya lọ tí ojú egbò kò san tí ẹ̀jẹ̀ kò dáwọ́ dúró tí wọn ń rìn bẹ́ẹ̀ kiri. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo àwọn ara ọ̀run Àpáàdì ló ń jẹ irú oró tí a sọ wọ̀nyío, àwọn tí wọn ń jẹ irú ìyà báwọ́nonnì ni àwọn tí wọ́n ti jẹ́ alágbára ní ìgbà ayé wọn ti wọ́n sì ti lo agbára wọn láti fi dá ọmọ ẹlòmíràn lóro irú èyí tí a dárúkọ gbogbo. A dé ibi tí a bá ọkùnrin kan tí ó rọra jókòó ní òun nìkan tí o ń sọkùn tí ẹnikẹ́ni kò sí ni agbegbe ibi tí ọkùnrin náà wà rárá, ìgbà tí Èṣù si fi í han adéforítì ó ní, ‘Olówó pátápátá ni eléyìí nígbà tí ó wà ní ayé ṣùgbọ́n kò fi owó rẹ̀ ṣe ẹnikẹ́ni lóòre, ó lé gbogbo ènìyàn kúrò lọ́dọ̀ rẹ, kìí fẹ́ kí ẹnikẹ́ni súnmọ́ òun. Nísisì yìí, ó ti kú, ó wá sí ọ̀dọ̀ mi, o ń wa kí òun tilẹ̀ bá ẹnìkan sọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan ṣùgbọ́n kò rí, o di ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún tí o ti dé ibi tí ó wà yìí láì sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni.’ Onírúurú ẹ̀dá ni o ń jìyà ní ọ̀run Àpáàdì, a rí bàbá tí ó yìnbọn pa ọmọ rẹ̀ láyé, ìyá tí fún ọmọ ní òogùn jẹ láti fi pa ọmọ, àbúrò tí ó lu ẹ̀gbọ́n pa àti ọ̀kẹ́ àìmọye ìwà burúkú gbogbo tí àwọn ọmọ ènìyàn ń hù. Ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ láyé, a! Ẹni tí ó bá fẹ́ mọ̀ bí ọmọ ènìyàn ti burú tó kí Olúwarẹ̀ lọ sí ọ̀run Àpáàdì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè fi ẹnu ara rẹ̀ sọ, tàbí kí ọwọ́ kọ́wọ́ kọ sílẹ̀ fun àti kà wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n inú Èṣù pàápàá kìí dùn láti ṣe ibi ko si ń le ṣe ibi láì jẹ́ pé ọmọ ènìyàn fún un ní ààyè.òun pàápàá wí fún Adéforítì ó ní, ‘A, Adéforítì, inú mi kò le dùn láéláé nítorí èmi pàápàá ń fẹ fi ibi ṣíṣe sílẹ̀ n kò le fi i sílẹ̀ ni. Ìbẹ̀rẹ̀ ni n ko ti tètè kó ara mi ní ìjánu ṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ ní ibi kékeré ṣùgbọ́n díẹdíẹ ni ìwá búrúkú mi ń bi si i tó bbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé, lónìí yìí, tí ó ti tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn tí mo ti ń hùwà ibi wọ̀nyí, ó ti di àṣà mi gan-an ó ti di oúnjẹ fún mi, èmi pàápàá mọ̀ pé ìwà tí mò ń hù kò lè ṣe mi ní ànfàání, ṣùgbọ́n àti fi ìwà wọ̀nyí sílẹ̀ kò ṣe e ṣe. Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, kì í ṣe ìgbà gbogbo ni mo ń rí ààyè láàrin àwọn ọmọ ènìyàn, nítorí bí ọmọ aráyé kò bá ti fi ààyè sílẹ̀, bí ó ti wù tí mo sa ipá tó n kò lè rí ààyè láàrin wọn. Mo rántí ní àìpẹ́ yìí tí mo ń ti ọkùnrin kan kí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin òun àti aya rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà alákọrí obìnrin yìí tutù jù fùn mi, bí ọkọ ba ti ń sọ̀rọ̀ líle ni òun ń sọ̀rọ̀ rírọ̀, bí ọkọ ti ń fajúro ni òun ń rẹ́rìn-ín, ìgbà tí ó ṣe, ọkọ pàápàá lé mi kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ̀, mo ba tún bá ìrìnkiri mi lọ.’ Ìgbà tí Èṣù parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, Adéforítì rí i pé àkókò ti lọ, ó wí fún Èṣù kí ó mu òun lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn lébìrà tí òun ń fẹ́ nítorí òun fẹ́ tètè padà. Èṣù náà bá mú u lọ, ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wa nígbà tí a dé ibẹ̀ tí ó jẹ́ pé àwọn ẹranko ni a bá, kìnìhún, àgbọ̀nrín, ẹkùn, ìkóòkò, ẹfọ̀n, erin, màlúù, ràkúnmí, esin, àgùnttàn, ewúrẹ́, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ajá, ológbò, èkúté, òkétá àti àwọn bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n ìgbà tí Èṣù dé ibẹ̀ tí ó nawọ́ sókè báyìí, tí ó ní kí méjìlá nínú wọn jáde, ṣe ni a ri tí àwọn ẹranko wọ̀nyí yípadà tí wọ́n di ènìyàn. Ó fi méjìlá nínú wọn fún Adéforítì, o tún rẹ́rìn-ín kékeré báyìí ó ní, ‘Èmi ni mo sọ wọ́n di ẹranko, mo ti mú wọn kúrò nínú ipò ènìyàn, wọn kò gbọdọ̀ kúrò ni ibi tí o ti rí wọn yìí, mò ń lò wọ́n fún iṣẹ́ ṣse ni’. Lẹ́yìn èyí, o ní, ‘Ẹ padà sí ipò yin’were ni gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí tún ti yípadà tí wọ́n di ẹranko àfi àwọn mejìla tí o fi fún Adéforítì ni Adéforítì mú wa sí ilé rẹ̀. Báyìí ni a rí bí ọ̀run Àpáàdì ti rí. ibi burúkú ni. Pẹ̀lú ayọ̀ ni àwa náà fi padà bọ̀, nítorí ṣe ni gbogbo ibẹ̀ ń rùn ṣùù, kò sí nǹkan kan tí ènìyàn rí tí ó bá ni lójú mu, kò sí orin kikọ, kò sí ẹ̀rín rírín, kò sí kí ènìyàn bá ẹnìkejì ṣiré, ìbànújẹ́ kún ibẹ̀ dé ẹnu. Bí a ti padà dé Àjùlé ọ̀run tí a ṣí fìlà àìrí orí wa, tí ìyá Adéforítì wá tí Adéforítì ń jíṣẹ́ fún un, ni ọkùnrin arẹwà aláṣọ funfun kan wọlé, àṣé ìránṣẹ́ Olódùmarè ni bí ó ti wọlé ni a ri i tí ó ba adéforítì sọ̀rọ̀ ní èdè tí àwa kò gbọ́, àfi ìgbà tí ó sì máa jáde tí ó ju ọwọ́ sí apá kan báyìí tí a déédéé wo ibi tí ó ju ọwọ́ sí tí a rí ogunlọ́gọ̀ ohun èlò iṣẹ́. Ìgbà tí ó lọ tan ni Adéforítì sọ fún wa tí ó wí pé ìránṣẹ́ Olódùmarè ni àti pé ṣe ni ọba ọ̀run ránṣẹ́ wá sọ fún òun pé òun kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àwọn lébìrà tí òun mú ti ọ̀run Àpáàdì wọ̀n-ọnnì dé ibi ilé Ìgb éga-ọ̀run rárá nítorí ìrańṣẹ́ Èṣù kò gbọdọ̀ dé sákání Ọlọ́runn ọba. Ó tún wí pẹ̀lú pé gbogbo àwọn ohun èlò tí a rí wọ̀n-ọnnì, Ẹlẹ́dàá ló fi wọ́n ránṣẹ́, àwọn ni idá ìṣẹ́gun, àáké ìṣẹ́gun, ọkọ́ ìṣẹ́gun, akeǹgbè ìṣẹ́gun. Ó wí pẹ̀lú pé nísisì yìí tí òun ti rí ohun èlò wọ̀n-ọnnì a kò ní ba òun lọ síbẹ̀ ní ọjọ́ kejì kí á wá lọ wòran. Ìgbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, a lọ ó dí ibẹ̀. Bí Adéforítì bá sì ti mú àdá yìí tí o fi gé ewéko kan, ṣe ni àdá a sá jáde lọ́wọ́ rẹ̀ tí àdá a máa tìkara rẹ̀ ṣiṣẹ́ lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àáké, bẹ́ẹ̀ ni ọkọ, bẹ́ẹ̀ ni akeǹgbè, kí a má sa fa ọ̀rọ̀ náà gùn lọ títí wákàtí kan ni ile náà gba Adéforítì tí ó bá òkè ọ̀run lọ. Ilé yìí ga ti n kò rí irú rẹ̀ rí, ó lẹ́wà rékọjá ààlà kò sì sí ẹni tí ó lè ka iye iyààrá inú rẹ̀ tán. Lẹ́yìn è’yi, a padà bá ilé Adéforítì lọ, ṣùgbọ́n mo fẹ́ sọ fún yín pé ìgbà tí mò ń sọ̀rọ̀ ‘Ọjọ́ kejì’ ọjọ́ kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ awa ti a jẹ́ ọdẹ ni a n kà á bẹ́ẹ̀, ìgbà tí ó bá pẹ́ títí tí oorun ba kun ni ti a sì tún jí ni àwa ń pè ní ọjọ́ kejì, ṣùgbọ́n Adéforítì àti ìyá rẹ̀ kò sùn rárá, ilẹ̀ kìí sí í ṣu ní ibẹ̀ pé kí ènìyàn déédéé rí òkùnkùn, ṣe ni gbogbo ilé ń mọ́lẹ̀ títí ọjọ́ ayé láàárò, lọ́sàn-án, lálẹ́, lọ́gànjọ́ òru. Ìgbà ó tó bí ọ̀sẹ̀ kan tí a ti de ibẹ̀ mo wí fún iwin ọ̀rẹ́ wa yìí pé a fẹ́ máa lọ sí ìrìnàjò wa. Ìgbà tí o sì ti kí wa dáadáa tí ìyá rẹ̀ náà ti sure fún wa tán ni o ṣí ìlẹ̀kùn kan báyìí fún wa. Jíjáde tí a jáde, ojú ọ̀nà òkè Ìrònú ni a jáde sí, ní ibi tí a ti kọ ri i . WÈRÉDÌRAN TÍ Ń GBÉ ILÉ ÒMÙGỌ̀PARAPỌ̀ A kọjú sí ọ̀ná wa, à ń lọ, a kò sì rí nǹkan kan jù bẹ́ẹ̀ lọ títí ó fi fi òwúrọ̀ ọjọ́ kan báyìí, ní nǹkan bí agogo mẹ́wàá, tí a rí ọ̀nà kan tí ó yà bá a pá ọ̀tún lọ. A rí àkọlé yìí, ó tọ́ka sí ọ̀nà náà: ‘Eléyìí ní ìlú àwọn Aláṣejù nibi tí ọba Aláyélúwà Aláṣetẹ́ ti ń ṣe ọba wọn.’ Orúkọ ìlú yìí kò fa nni mọ́ra, ṣùgbọ́n bí kò ti fa ni mọ́ra tó yìí náà, a fẹ́ láti lọ mọ ibẹ̀, nítorí a lè lọ dé ibẹ̀ kí a rí ọgbọ́n díẹ̀ kọ́. Ìgbà tí o kù díẹ̀ kí a wọnú ìlú náà, a bẹ̀rẹ̀ síí gbọ́ ariwo, ìgbà tí a sì dé ibẹ̀ ariwo náà ti pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àti gbọ́ nǹkan tí enikejì ń sọ ṣòro. Bí a bá mú ti ariwo yìí kúrò, ìlú náà dára, nítorí wọ́n ni mọ́tò, wọ́n ní kẹ̀kẹ́, wọ́n ni alupùpù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ọ̀làjú ni wọ́n ni. Ṣùgbọ́n àṣejù wọn nípa ètò ṣiṣe ti pọ̀ jù, ìlú ibẹ̀ ni mo ti mọ̀ pé kò sí nǹkan náà ní òde ayé yìí tí àṣejù rẹ̀ dára. Àṣe ètò ṣíse ní àṣejù nínú! Gbogbo ìlú náà po, wákàtí kan náà ni wọn ń lò láti jẹun, ìsẹ́jú kan náàni wọ́n ni láti bu òkèlè. Bí àkókò oúnjẹ ba ti ń tó, wọn ó lu agogo, wéré ọlọ́pàá á fọ́n ká inú ilé. Ẹni tí ó bá fi ìṣẹ́jú kan ṣáájú tàbí ìṣẹ́jú kan pẹ́ kí ó tó bu òkèlè, ẹ̀wọ̀n ni. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ sọkún láìjẹ́ pé ó tó àkókò ẹkún ní ìlú àwọn Aláṣejù. Bí ẹkún gbọn ni, bí kò gbọ ni, dandan ni kí olúwarẹ̀ ké hìíì! Hiìííí! Hìíìíì. Ní àkókò ẹkùn ní ìlú wọn. Àkókò ẹ̀rín wà lọ́tọ̀ pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ṣá ni gbogbo ètò wọn. Níbgà tí àkókò ẹkún kọjá tán tí mo wọ ilé ti wọ́n ti ń ta nǹkan báyìí, ọkùnrín kan wọlé, o kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó lọ́wọ́. Fìlà kan ni ó fẹ́ rà o, ṣùgbọ́n bí á ti dé ibi ti wọ́n ti ń ta ọjà tí o ri arẹwà wúndíà tí wọn ń ta ọjà náà, ti wọn ń mì, ti wọ́n ń yan níwájú rẹ̀, tí wọn ń pọ́n oun náà, tí wọn ń fi ọjà gbogbo hàn án, ó bẹ̀rẹ̀ síí náwó, ó ra gbogbo nǹkan tí kò ní èrò àti rà tẹ́lẹ̀, ó ná gbogbo owo tan, bẹ́ẹ̀ ni àpò owó méjì ló gbé wá. Mo bá bi ọkùnrin kan báyìí kí ó sọ fún mi orúko ọkùnrin tí ó ná irú owó yìí, ẹni tí mo bi léèrè wí fún mi pé òun ni ọ̀gbẹ́ni Wèrédiran ti ń gbé ilé Òmùgọ̀parapọ̀. Kò pẹ́ púpọ̀ tí Wèrédìran wá sí apá ibi tí mo wà tí ó sọ̀rọ̀ sí mi, a bá ara wa sọ̀rọ̀ dáadáa, èmi pàápàá tilẹ̀ ń fẹ́ láti bá a ṣe ọ̀rẹ́ ki n bà rí ààyè fún un ní ìmọ̀ràn díẹ̀, nítorí bí ó ti ṣe náwó yìí ko té mi lọ́rùn rárá. Kí a ma sa fà á gùn lọ títí, ó bèèrè ibi tí mo dé sí, mo sọ fún un, o sì sọ ibi ti òun náà ń gbé fún mi, ó wi fún mi pé òun n bọ̀ wá bẹ̀ mi wò ní ọjọ́ kejì. Nígbà tí mo kúrò nínú ilé tí mo ti lọ̀ ra nǹkan yìí, èmi àti àwọn enìkejì mi yí ìlú náà lọ. Ìgbà tí ó maa tó agogo mẹ́ta a padà sí ilé tí a wọ̀ sí. Wèrédìran ọ̀rẹ́ mi ti sọ fún mi pé ki n ma sàì jáde ní agogo márùn-ún wá wòran nítorí àkókò náà ni àkókò ijó. Nígbà tí o di agogo márùn-ún láàátọ́, gbogbo ìlú bẹ̀rẹ̀ sii jó a si ń gbọ́ ìlú lọ́tùn-ún lósì. Kò pẹ́ púpọ̀ tí a rí Wèrédìran tí o ń jó bọ̀. Ìlù bàtá lo ń jó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ síío lu ìlù báyìí, ‘Wèrádìran, ó jẹ gọngọ gbèsè, gbèsè, o jẹ gongo; nítorí wúndíá ó jẹ gọngọ gbèsè, ó jẹ gọngọ; nítorí adéblébọ̀, ó jẹ gọngọ gbèsè, gbèsè, o jẹ gongo; nítorí afẹ́ ayé ó jẹ gọngọ gbèsè, gbèsè, o jẹ gongo; nítorí àìnírònú ó jẹ gọngọ gbèsè, gbèsè, o jẹ gongo; nítorí fáàrí, ó jẹ gọngọ gbèsè, gbèsè, o jẹ gongo abbl...’ Báyìí ni wọn n lu ìlù náà, èyí tí o sì tilẹ̀ yà ni lẹ́nu ni bi Wèrédìran ti ń jó ijó ìyà náà tayọ̀tayọ̀, nítorí ìgbà tí àwọn ońlì bá fi ìlù wi pé ‘Wèrédìran, òun á dáhùn á ní ‘ó jẹ gọngọ gbèsè, gbèsè, ó jẹ gọngọ.’ Ìgbà tí ó tilẹ̀ ṣe o ní kí àwọn onílù máa ki òun àwọn bá bẹ̀rẹ̀ wọ́n ni, ‘Wèrédìran, ti ń gbe ilé Òmùgọ̀parapọ̀, Òmùgọ̀parapọ̀, Omùgọ̀parapọ̀, bí ó bá burú tán, ìwọ nìkan ni ó kù, ìwọ nìkan ni ó kù, ìwọ nìkan ní ó kù, Wèrédìran, Wèrédìran, Wèrédìran ọwọ́ epo ni aráyé ń bá ní í la, ọwọ́ epo ni aráyé n ba nii la, ọwọ́ epo ni aráyé níí la, wọn ko n bá ni láwọ́ ẹ̀jẹ̀, wọn ko n bá ni láwọ́ ẹ̀jẹ̀, wọn ko n bá ni láwọ́ ẹ̀jẹ̀ rá rá rá rá rá (ìlù tún sọọ́) Ìgbà tí ó di ọjọ̀ kejì, Wèrédìran wá bẹ̀ mi wò gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, èmi náà sì wí fún un pé n ó dé ilé rẹ̀ lọ́jọ́ kẹta èyí nì. Ìgbà tí ó di ọjọ́ kẹta mo múra ó di ilé Òmùgọ́parapọ̀ láti lọ̀ kí Wèrédìran. Ó dùn mi láti rí i pé ki ń to dé ibẹ̀ agogo ẹkun sísun ti lù, gbogbo ìlú sì ti bẹ̀rẹ̀ síí sọkún, ṣùgbọ́n nígbà tí mo dé ilé Òmògọ́parapọ̀ ni mo rí i pé ẹkùn gan-an ni àwọn ń sun. Nǹkan tí ó n pa wọ́n lẹ́kún nì yí; Ilé kan wà ní etí ilé òmùgọ́parpaọ̀ orúkọ ilé náà a máa jẹ́ Wọ̀bìáparapọ̀. Ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ pátápátá ni àwọn ara ilé Òmùgọ́parapọ̀ àti Wọ̀bìáparapọ̀ jẹ́, ọ̀rẹ́ náà jinlẹ̀ gidigidi. Gbogbo ara ile Òmùgọ́parapọ̀ ni o ní ìyàwó, ṣùgbọ́n àpọ́n ni wọn. Ìbànújẹ́ ńlá ló sì jẹ́ fún àwọn ara ilé Òmùgọ́parapọ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wọn ni ó ní ìyàwó, síbẹ̀síbẹ̀ ìyàwó wọn kan ṣosọ kò bímọ. Ó wá ṣe, ni àwọn ara ilé Wọ̀bìáparapọ̀ wí fún àwọn ọ̀rẹ́ wọn tí àwọn ìyàwó wọn kò bímọ yìí pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn ìyàwó wọn wọ̀n-ọnnì wá gbé ilé àwọn ni odidi ọdún kan kí àwọn bá wọn wá egbòogi tí ó dájú fún àìbímọ wọn wọ̀nyí, nítorí, ṣe kí a sọ òótọ́ kọ? Olóògùn ni gbogbo àwọn ara ilé Wọ̀bìáparapọ̀ jẹ, wọn kò sì ní èrò búburú kan lọ́kàn rárá nígbà tí wọ́n wí bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, ṣe gbogbo ènìyàn ni o máa ń gbàdúrà kí òun máṣe bọ́ sínú ìdánwò! Ẹni tí ó gbé ìdánwò ńlá ka ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ láyà ni ó wí pékí onítọ̀ún ṣe àbòsí òun. Lóòótọ́, àwọn ará ilé Wọ̀bìáparapọ̀ kó gbogbo àwọn obìnrin ilé Òmùgọ́dìran lọ sí ilé wọn, o sì de ọdún kan gbáko tí èyí ti sẹlẹ̀ gan-an ni èmi lọ kí Wèrédìran. Ọjọ́ kejì tí àwọn ará ilé Òmùgọparapọ̀ ti ń retí ìyàwó wọn ni mo dé ibẹ̀. Òw;urọ̀ ọjọ́ tí mo sì dé ibẹ̀ yìí ni àwọn ìyàwó ránṣẹ́ sí wọn pé àwọn kò wá mọ́ nítorí pé àwọn ti ní ọkọ mìíràn sí ilé Wọ̀bìáparapọ̀. Ìwé ni ìyàwó Wèrédìran tilẹ̀ kọ sí i, nígbà tí o sì fi ìwé náà hàn mì nǹkan tí wọ́n kọ síbẹ̀ ni èyí: “Ilé Wọ̀bìáparapọ̀ “Ìlú Aláṣejù “Ọjọ́ kẹtàlá, oṣu kẹjọ “Ní Ẹẹ́dégbẹ̀wá ọdún o “lé méjìléláàdọ́ta “lẹ́yìn ikú Olúwa wa. “Sí “Ọ̀gbẹ́ni Wèrédìran “Ilé Òmùgọ́parapọ̀. “Wèrédìran mi Ọ̀wọ́n, Bí emi àti baálé mi ti fi ẹ̀ọ̀ ẹran jẹun tán ní òwúrọ̀ yìí, tí ìṣaasùn ọbẹ yí mi ká, tí ìkókó èlùbọ́ fẹ́yìntì ni yààrá, tí àkàṣù ẹkọ sì kún ilé mi kítikìti, mo tọrọ ààyè lọ́wọ́ ọkọ mi tuntun náà láti kọ ìwé yìí sí ọ. Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún mi ní alẹ́ àná nígbà tí wọ́n wí fún mi pé ìwọ ní ki n wa fi ojú gán-án ní rẹ, nítorí láìṣee àníàní, àti ajá àti ẹran ní ilẹ̀ yìí ni ó ti mọ̀ pé èmi kò ní nǹkan ṣe pọ̀ pẹ̀lú ilé Òmùgọ́parapọ̀ mọ́, ewúrẹ́ ilé ibẹ̀ kò gbọdọ̀ dé sàkání mi. Bí mo ti ń kọ̀wé yìí, ojú mi ń wo ọkọ mi tuntun, ẹni ti ó dúró rọ̀gbọ̀dọ̀ kanlẹ̀, ẹni tí ó pupa bí epo inú ṣágo, ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́, awẹlẹ́wà, ọ̀dágọ̀dọ̀, ìbàdì àrán, báálé mi àpé. Bí mo ti ń kọ̀wé yìí, mi tuntun náà ń fi ojú pè mí, ó sì d[bí ẹni pé ojjú wọ̀n-nnì ń wí fún mi pé lemọ́lemọ́ báyìí pé, ‘Wò mi pe e, wò mi sùn, ọdọ rẹ ni mò ń bọ̀’ Mo tàn mọ̀ ọ́ pé kò ni ṣàì dùn mọ́ ọ nínú láti gbọ́ pé oyún oṣù mẹ́fà ni ń bẹ ni inú mi, mo sì ní láti gbọ́ pé láti wí fún ọ pé bí mo ti ń ṣe àkíyèsí oyún mi yìí, ọkùnrin méjì gbààgì gbààgì ni mo ggbé sí ikùn mi, tó bẹ́ẹ̀ ti, bí Ọlọ́run bá sọ̀ mi lérù àǹfààní kalẹ̀ t’qan, a kò ni ṣàì wí nípa ti baálé ni tuntun náà pé: “Bàbá ìbejì ni ọkùnrin yìí ń ṣe” Owó mi ìjọ́sí n kọ́? Owó tí o yà lọ́wọ́ mi nígbà òkú ìyá rẹ, ọ̀rọ̀ náà bí àwọn àbúò ọkọ mi nínú nígbà tí mo rò fún wọn, mo sì gba ọ níyànjú wí pé kí ó tètè fi owó náà sọwọ sí mi, nítorí kí ó má ba jẹ pé iwọ yóò déédéé rí àwọn ara ilé ọkkọ mi láìròtẹ́lẹ̀, kí wọn sì gba owó náà tagbára. N kò lè ṣàì gbà ọ́ níyànjú nípa ti ìdọ̀tí ilé rẹ, ọ̀bùn ọ̀nà rẹ àti èérí ara rẹ pẹ̀lú. Nítorí nǹkan ti yí padà, n kò dàbí ti àtẹ̀yìnwá, ojú mi ti là bí ojú ẹni ti ń kiri ẹ̀yìn odi, ìwà mi ti di gbajúmọ̀, n kò hùwà bí òmùgọ̀ mọ́, mo ti kúrò ni ipò ará oko. Nítorí ìdí èyí, mo bẹ̀ ọ nítorí Olódùmarè, tẹ́tí sílẹ̀ ki n bá ọ sọ̀rọ̀ méjì tàbí mẹ́ta: àwo ti ẹnikẹ́ni ko fọ̀ láti ayébáyé, máṣe fi mmu omi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìà rẹ àtijọ́, ọbọ̀ tí kò ni epo, tí kò ní iyọ́ m€tàdínlọ́gbọ̀n nínú ayé kò yẹ ọmọ ènìyàn, yé é bá àwọn ará ile Òmùgọ́ parapọ̀ tọ́ ọ wà, gẹ́gẹ́ bí ìwà wọn. Okele tí ọ̀nà ọfun bá gbà ni ènìyàn n fi sí ọ̀nà ọ̀fun, òkèlè tí ó tóbi bí orí Ọmọdé kò ní ṣàì yọ di ni lẹ́nu, rọra máa bu òkèlè nígbà tí o ba ń jẹun. Èékán ọwọ́ rẹ a máa dúdú fún èérí, nítorí ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni ìwọ ń ré e, irún orí rẹ dàbí ìtàkùn ara igi nítorí ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni ìwọ ń já a, ara rẹ̀ dúdú bí ìdí ìkòkò, nítorí ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni ìwọ ń wẹ̀ ẹ́. Máṣe hùwà àbùkù bí irú ìwọ̀nyí mọ́, kí ìwọ bà rí obìnrin fẹ́ ọ. Èmi pàápàá ti yi ìwà mi padà, n kò hùwà bi ti ilé Òmùgọ́parapọ̀ mọ́, oṣù mẹ́ta mẹ́ta ni mò ń run orin nísisì yìí, oṣù mẹ́ta mẹ́ta ni mò ń ré èékán mi, ti mò ń wẹ̀, ti mo sì ń tọ́jú irun orí mi. Ara mi sì ti yípadà, mo ti ń di pupa, eyín mi sì ti ń di funfun. Ìba díẹ̀ ni kúrúnà kù, egbò kò wọ́pọ̀ mọ́, ìfọ̀n ń tan lọ, bẹ́ẹ̀ ni ara mi si ń dán sii. Àwọn ọkuǹrin tì o ń kí mi nísisì yìí lé ni ẹgbẹ̀rún, àwọn obìnrin tí o ń yẹ́ mi si lé ni ẹgbẹ̀jọ́. Ọjọ́ wo ni ìwọ ń bọ̀ wá kí baálé mi? Ọjọ́ mẹ́sàn-án òní n kọ́? Nítorí kò ní rí ààyè dá ọ lóhùn lọ́jọ́ mìíràn, òun ni Mọ́gàjí ilé wa. Ní ọjọ́ tí ìwọ bá sì ń bọ̀ pẹ̀lú, máṣe gbàgbé àti di ẹrù mi tí ó kù bọ̀, kí ìwọ gbé e lé àtàrí rẹ, kí inú baálé mi ba a lè dùn sí ọ. Nígbà tí ìwọ bá sì dé náà ń kọ́, máṣe máa bọ̀ nínú ilé mi tààrà, ki àbùkù má ba kàn ọ, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, bí ìwọ dúró lẹ́yìn òde títí èmi yóò fi rí ọ, nígbà tí mo bá rí ọ tán, tí mo bá sì mú ọ wọle, máṣe gbàgbé láti kí baálé mi pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, nítorí bí ìwọ kò bá ṣe eléyìí nì, bí ìwọ bá gba ojú ọ̀nà wọlé, ojú fèrèsé ni ìwọ yóò gbà jáde. ‘Bá mí kí àwọn Òmùgọ̀ ti ń bẹ nínú ilé Òmọ̀parapọ̀ wọ̀n-ọn-nì. “Èmi ni ìyàwó rẹ àtijọ́, “Ayédiméjì. Báyìí ní ìwé tí ìyàwó Wèrédìran kọ sii ri, ìgbà tí mo sì ti jókòó díẹ̀ nínú ilé náà lẹ́yìn èyí ni mo ti múra ti mo n lọ. Wèrédìran rọ̀ mi ki n jẹun ṣùgbọ́n n kò jẹun, n ko le jẹun ìbájẹ́ ilé Òmùgọ́parapọ̀. Nígbà tí mo dé ilé tií a wọ̀ si ni ìlú náà mo ròyìn fún àwọn ọ̀rẹ́ mi. Ẹ̀rín pa wọn díẹ̀ ṣùgbọ́n kò sí ẹni ti kò dá àwọn ará ilé Òmùgọ́parapọ̀ lẹ́bi fún ìwà òmùgọ̀ tí wọn hù, àwọn ni wọn fi ọwọ wọn fa ìjàngbọ̀n tí wọ́n bá ìjàngọ̀n pàdá tí wọ́n sọ ènìyàn di màlékà tí wọn gbàgbé pé ẹlẹ́ran ara ni àwọn ara ilé Wọ̀bìáparapọ̀ i ṣe. Ọjọ́ kejì ni a kúrò ní ìlú àwọn Aláṣjù. Akẹ̀ nínú àwọn ènìyàn wa tilẹ̀ dá àbá pé kí a lọ kí Aláṣetẹ́ ọba wọn, ṣùgbọ́n nígbà tí a rántí Òmùgọ̀dìmejì àti Òmùgọ́dimẹ́ta àwọn ọba Èdìdàrẹ́ àti ohun tí ojú wa rí ílú wọn, a pínnu, pé a kò ni lọ. A múra a kọ́jú sí ọ̀nà wa, sí òkè Ìrònú ti ń bẹ nínú Igbó Elégbèjè.’ ÌGBÉYÀWÓ ÌRÌNKÈRINDÒ PẸ̀LÚ ÀBÚRÒ OLÓKUN IWIN INÚ OMI Ṣ ùgbọ́n ki ní kan kò ní ṣàì yà yín lẹ́nu nípa èmi pàápàá, ẹ kò bi mi nǹkan náà dan? Òhun ni wí pé láti ìgbà tí a ti kúrò ní ibi ti Ẹlẹ́gbára ti lé wa, ọkàn mi kò kúrò lára obìnrin tí ó ṣe ìtọ́jú mi nígbà tí Ẹlẹ́gbára fi le mi kọjá òkè odò. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ ṣáájú, n kò fẹ́ràn obìnrin ṣáájú àkókò náà, wọn tilẹ̀ n máa rùn sì mi ni, n kò sì mọ ohun tí ó fa ti fífẹ́ tí mo déédéé wá fẹ́ràn obìnrin náà ju ti ìtọ́jú mi tí o ṣe nígbà náà lọ, ṣùgbọ́n kí má sa fà á gùn lọ títí, góńgó orí ẹ̀mí mi ni ọmọ náà dúró lé, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kìí síí kírò lẹ́nu mi tó bẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé àwọn enìkejì mi máa ń fi mi ṣe yẹ́yẹ́ ṣa ni. Èyí tí ó dùn mi jùlọ rékọjá gbogbo rẹ̀ ni pé n kò lo àǹfààní tí mo ni tó nígbà tí a jọ rí ara wa, àkókò tí ìfẹ́ tẹ̀ sì ń gùn mi bí ẹni gun ẹsin yìi’, n kò ríi mọ. Ìbànújẹ́ nípa èyí wọ̀ mi lọ́rùn bí ẹni wọ ẹ̀wù ni, bẹ́ẹ̀ ni ìwà rẹ̀ ló lọ gbé ìfẹ́ mi dìde nibi ti ìfẹ́ mi ti sùn sí. Nígbà tí ó pẹ́ tí ara mi kò gbà á mọ́, mo wí fún àwọn enìkejì mi pé obìnrin náà ti ta ọfà ifẹ́ lù mi, àti pé oró ọfà náà ti bẹ̀rẹ̀ síí mú mi. Nígbà tí wọn sì tún máa ṣe yẹ̀yẹ̀ ń kọ́, wọn ní ó pẹ́ tí àwọn náà ti ń wò mi ti ìfẹ́ náà ń tì mi kà bí ẹni tí ẹmu ń pa kí, orí mi má sa jẹ́ ki ìfẹ́ tì mi sí kòtò ni. Fìlásayépọ̀ wá sọ fún mi lẹ́yìn náà pé òun lé bá mi ṣe e kí iwin inú fìlà òun lọ bá mi kí obìnrin náà wá, Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, wéré ni mo dọ̀bálẹ̀ fún Fìlásayépọ̀, èmi ni mo mà sì jẹ́ olórí gbogbo wọn o! – A! Ìfẹ́ mà burú o, o burú púpọ̀. Ìfẹ́ mú mi dọ̀bálẹ̀, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi gbọn ipàntí àti eruku igbá àyàmi, wọ́n rọra rẹ́rìn-ín, wọn ń ni, [Ẹ rọra o, ọ̀gá, ẹ rọra o, ọ̀gá’ ‘Ẹ rọra’ yẹ̀yẹ́ ni wọ́n ń wí. Gbogbo ènìyàn ko sì tilẹ̀ tó ti ọ̀gbẹ́ni Ìrèké, o fi mi ṣe ẹgbẹ̀rún-un yẹ̀yẹ̀ ní ìdí ọ̀ràn náà. Kí a ma sà fà á gùn lọ títí, iwin inú fìlásayépọ̀ bá mi lọ sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà, o lọ kíi fún mi. Wéré ló ti tí o sì bọ̀. Nígbà tí o ń bọ̀ ó gba ìwé kan bọ̀ wa fún mi, ohun tí ó wà nínú ìwé náà ni èyí: “Odò Ìrántí “Ní ìtọ́jú Ẹbọra olókun “ Ọjọ́ kẹẹ́dógún oṣu kejìlá “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́wá ọdun ó lé “Méjìléláàdọ́ta lẹ́yìn “Ikú olúwa wa “Ìrèké mi ọ̀wọ́n, Mo yọ̀ pupọ̀ nígbà tí mo rí oníṣẹ́ rẹ nítorí ó pẹ́ tí mo ti ń ṣe àníyàn wí pé ki n tilẹ̀ mọ bí o ti rìn, àfi bí ẹnipé o dé ọkàn mi ni. Ẹ kú atijọ o, kí ni ṣe tí ó pẹ tó bẹ́ẹ̀ kí ẹ tó kúrò ni ìlú àwọn Èdìdàrẹ́ . mo rò pé ẹ ṣe iṣẹ pàtàkì níbẹ̀ ni. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ki yín púpọ̀. Kí ẹ bá mi kí àwọn ọ̀rẹ́ tiyín náà. Nǹkan tí ẹ bá jẹ kù, kí ẹ máa fi tiwa ránṣẹ́ sí wa o. ‘n kò rí ààyè kọ̀wé púpọ̀ nínisì yìí,’ Èmi ni tiyin Ìfẹ́ pàtàkì. Nígbà tí mo rí ìwé yìí, àfí bí ẹni pé wọ́n fi mi jọba ni. Mo kà á lẹ́ ẹ̀ kín-ín-ní, mo kà á lẹ́ẹ̀kejì, mo kà á lẹ́ẹ̀kẹta, n kò ṣàì lè sọ iye ìgbà tí mo kà á tán. Mo gbé e fún àwọn ọ̀rẹ̀ mi, a jọ kà á, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe oríṣìíríṣì ìbéèrè. ‘Ń jẹ́ o kò gbádù ìwé náà? Ǹjẹ́ èyí tí ó kọ sẹ́yìn yìí kò fi ìfẹ́ hàn tó, ‘Nǹkan tí ẹ bá jẹ́ kù kí ẹ máa fi tiwa ránṣẹ́ sí wa o’? Ǹjẹ́ bí ó bá fẹ́ràn mi kò ni wí pe àáró mi sọ òun gan? Nǹkan tí mò wí ni pé bí ó bá jẹ́ pé ó lè fẹ́ mi, kí á tilẹ̀ ní mo wí pé mo fẹ́ fẹ́ ẹ? Ṣùgbọ́n ó béèrè àlàáfíà mi o. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nǹkan ṣe! Nǹkan ṣe sí ọ̀nà Igbó Elégbèjè, nǹkan ṣe.’ Lẹ́yìn èyí, mo pe iwin inú fìlà Fìlásayépọ̀ mo bẹ̀rẹ̀ si i ṣe ìbéèrè wọ̀nyì lọ́wọ́ rẹ̀: ‘Níbo ló wà nígbà tí ori i? ‘O bá ìyá rẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ bí’? kí lo ti wí ná nígbà tí ó rí ọ? Ǹjẹ́ kò béèrè bí ara mi ti le sí? Ǹjẹ́ kò rẹ́rìn-ín nígbà tí o jíṣẹ́ fún un? ṣe kò rán ọ níṣẹ́ mìíràn sí mi? Kò bèérè ijọ́ tí a o dé? Abbl. Irú ìbéèrè bá wọ̀nyí ni mo ṣe lọ́wọ́ iwin náà, ibi tí mo sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ lo ti sọ fún mi pé ó béèrè bí mo bá kọ̀wé sí òun tàbí n kò kọ àti wí pé òun sọ pé n kò rí nǹkan fi kọ̀wé. Ìgbà náà ni iwin náà tó rántí pé ó fi ohun ìkọ̀wé ránṣẹ́ sí mi pé bí mo ba fẹ́ kọ��wé sí ẹnikẹ́ni lójú ọ̀nà ki ń máa lò wọ́n. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, n kò lè sọ bí inú mi ti dùn tó nígbà tí iwin náà jíṣẹ́ báyìí fún mi, oúnjẹ tí mo jẹ yàtọ̀ lọjọ́ náà, ara mi sì yà ju bí ti ń yá rí lọ. Inú ọmọ náà ni mo rò títí ilẹ̀ fi ṣu ìgbà tí mo sì máa lá àlá òun ni mo lá a rí, mo rii a jọ ń gbé ibi kan bí tọkọtaya. Ìgbà tí mo jí tí mo rọ́ àlá mi yìí fún àwọn ènìyàn mi, wọ́n ní àlá burúkú ni, wọ́n ní bí mo ti rí i tí a jọ ń gbé lójú àlá kò dára, èyí nì ni pé a kò ni jọ gbé pọ̀ bí tọkọtaya. ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ yìí kúrò ní kékeré, nítorí mo fẹ́rẹ̀ kú níbi tí wọ́n ti ń túmọ̀ àlá náà fún mi n kò sì jẹun títí ilẹ̀ ọjọ́ kejì fi sú nítorí àlá náà. Èyí tí o tilẹ̀ tún pa ni lẹ́rìn-ín ni pé n kò kí Inúlayéwà tó túmọ̀ àlá náà fún mi mọ́, bí ó ba kọjá n kò jẹ́ ki i, bí ó fi ẹsẹ̀ kọ n kò jẹ́ wí pé kí o pẹ̀lẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ṣe títí ilẹ̀ ọjọ́ náà fi ṣu. Nígbà tí mo tún sún lálẹ́ mo tún lá àlá ri i, mo ri i pe a bẹ̀rẹ̀ si i jà, àti wí pé a túká, òun ń lọ sí apá kan èmi náà ń lọ sí apá kan. Inú mi dùn rékọjá nígbà tí mojí, nítorí gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ tí àwọn ènìyàn mi ti ń ṣe, àlá eléyìí nì dára, èyí nì ni pé a o jọ bá ara wa rẹ. Bí mo ti jí lọ́jọ́ kejì mo ti yára ké sí Inúlayéwà mo ní, ‘Mo ti lá àlá mìíràn, a ti jà, a ti jà, lójú àlá’. Àwọn ènìyàn wa sì wá, mò pé oorun ìfẹ́ ni mo wa ń sùn ní tèmi, wọ́n dá mi ní inú dùn, wọ́n ní, ‘Àlá rẹ dára, Ìrìnkèrindò, àlá rẹ dára, ẹ o fẹ́ ara yín’. Kí n ma sà bá ọ̀rọ̀ gùn lọ títí, èmi náà fèsì ìwé tí Ìfẹ́pàtàkì kọ, nǹkan tí mo sì kọ ni èyí: “Ojú ọ̀nà oke Ìrònù ti n bẹ “Nínú igbo Elégbèjé “Ọjọ kẹrìndínlógún “Oṣu kejìlá “Ẹ̀ẹ́dégbẹ̀wá ọdún ó lé “Méjìléláàdọ́ta lẹ́yìn ikú “Olúwa wa. Ìfẹ́pàtàkì Tèmi Ọ̀wọ́n, Ki n tó máa bá ọ̀rọ̀ mi lọ, mo níláti kọ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fín ìwé yin tí mo rí gbà láìpẹ́. Mo sì rò pé ẹ̀yìn náà yóò mọ̀ bí mi ti rí sí yín ki ó tó di pé mo níláti ránṣẹ́ wí pé kí wọ́n lọ wò yín wá fún mi. Àfi Ọlọ́run ọba nìkan lo lè mọ̀ bí ọkàn mi ti rí láti ìgbà tí mo ti fi yín silẹ̀. Kò sí ọjọ́ kan láti ìgbà tí mo ti kúrò lọ́dọ́ yín tí n kò rántí rárá, wákàtí kan kò tilẹ̀ rékọjá láì pé mo ronú nípa yín, orí ẹ̀mí mi ni ẹ dúró lé, n kò sò le mu yín kúrò lọ́kàn rárá. Ṣùgbọ́n n kò fẹ́ kí ẹ ni èrò pé bẹ́ẹ̀ ni gbogbo obìnrin rí sí mi rárá-ó tì 0- kìí ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ó tó di pé a mọ ara wa, obìnrin máa ń rùn sí mi ni - ẹ jọ̀wọ́ kí ẹ forijì mí- ṣùgbọ́n òótọ́ ni mo sọ, bí ìgbọ̀nsẹ̀ ni obìnrin ti máa ń rùn sí mi. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tiyín ti yàtọ̀ pátápátá, tiyín yìí lo sì wá fi hàn mi pé, ìwà ènìyàn ń pè ni ìfẹ́, ìfẹ́ kò lórúkọ méjì. Aájò mi tí ẹ ṣe ní ọjọ́ tí Ẹlẹ́gbára fi lé mi tí mo já lu omi kò le ṣé e gbágbé bí mo tilẹ̀ gbàgbé ẹ̀yin pàápàá. Ńjẹ́ bí Ẹlẹ́gbára bá ti pa mi ni ijọ́ náà, ta ni ìbá máa jẹ́ Ìrìnkèrindò lónìí! – A! Ìwà ni ìfẹ́, ẹ ti fi ìwà yín gbin èso ìfẹ́ sí inú mi, èso náà hù, ó ti ní ẹ̀ka, ó ti ní ewé, o sì ti ní gbòǹgbò, ó gbalẹ̀ kankan nínú mi tó bẹ́ẹ̀ tí n kò lè mu ọkàn kúrò lára yín mọ́. Bí mo ti ń kọ̀wé yìí, ẹ̀yín ni ó ára jù lọ lode ayé lójú mì: orí yín wù mi, ọrùn yin wù mi, irun ori yin wu mi, èékán ọwọ àti ẹsẹ yin ń wù mi, iwájú yín dára, ìpàkọ́ yín dára, ẹyìnlójú yín dara, ipéǹpéjú yín dára, eyín yín dára, ètè òkè àti ti ìsàlẹ̀ yín dára pẹ̀lú, mo fẹ́ràn apá yin, mo fẹ́ràn ẹsẹ̀ yín, mo fẹ́ràn orukun yin, mo fẹ́ràn ọrùn ẹsẹ yín, àtẹ́lẹwọ́ àti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dára ju ti ẹnikẹ́ni lọ. Ẹ̀yìn yín bá ẹ ba ń kọja àti iwájú yín bí ẹ ba ń bọ̀ jẹ́ ohun iyí pàtàkì lójú mi. Ìdìde yín ń mu kí ọmọ ẹlòmíràn fẹ́ kí òun dìde, ìsọ̀rọ̀ yín ń mú kí ọmọ ẹlòmíràn fẹ́ sọ̀rọ̀, ijókòó yín mu kí ọmọ ẹlòmíràn fẹ́ jkókòó, ìrìn ẹsẹ̀ yín sì dàbí ẹni pé kí ènìyàn máa fi ẹsẹ̀ rìn láéláé ni. Nígbà tí mo rí yín ni ijọ́sí, aṣọ tí ẹ ró dàbí ẹni pé wọn bí yín mọ́ ọ ni, èwù tí ẹ wọ̀, dàbí ẹ̀wù ọba pàtàkì, gèlè tí e wé dàbí òkúta olów�� iyebíye, bẹ́ẹ̀ ni odidi ọjọ́ mẹ́fà ni mo fi la àlá rí ìborùn yín. Ẹkùn kò mọ iyì ara rẹ̀, ẹ kò mọ̀ bí ẹ ti n’iyi tó lójú àwọn ọmọ aráyé, nítorí n kò mọ̀ bí mo ti le ṣe àpèjúwe yín jù wí pe nígbà tí mo fi ojú inú wò yín láti òkè dé ìsàlẹ̀, ẹ dàbí ìgbà tí òòrùn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ní òwúrọ̀ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, ìmọ́lẹ̀ ológo rẹ̀ sí ara onírúurú àwọn nǹkan tí ń bẹ ní orí ilẹ̀ ayé, àwọn arẹwà kòkòrò, àwọn ẹranko dídára, àwọn ẹyẹ tí ó wu ni àti onírúurú gbogbo ẹ̀dá alààyè, àwọn ẹlẹmìí àwọn aláìní ẹ̀mí – bẹ́ẹ̀ ní ẹ rí, ọ̀rẹ́ mi tòótọ́, Ìfẹ́pàtàkì tí ó gbin ifẹ́ sí mi lọ́kàn, tí ìfẹ́ ń gùn mi ká bí kẹ̀kẹ́, tí o ń gbé mi kiri bí mọ́tò, tí o ń ti mí síhin-ín, tí mí sọ̀hùn-ún bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù bá ń fẹ́ igi oko. Mo ò pé ẹ̀yin náà ó wá rí i, nípa gbogbo srs tá mo sọ yìí, irú ipò tí ẹ wà, lọ́kàn mi, mo sì bẹ̀ yín tọkàn tọkàn wí pé kí ẹ máṣe bínú láti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí n ó ba a yín sọ nípa irú ipò tí mo wà yìí. Ìfẹ́pàtàkì, Ìfẹ́pàtàkì ni ọ̀wọ́n, ṣe ẹ kò fẹ́ ki n kú láìròtẹ́lẹ̀? Láìṣe àní àní, èmi náà mọ̀ pé ẹ kò fẹ́ bẹ́ẹ̀, dípò eléyìí nì, àfi ọ̀tá mi ni ẹ lè ni èrò burúkú sí. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ẹ kò fẹ́ nǹkan burúkú sími, mo fẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀ràn mi yìí ní àṣepé, kí ọjọ́ náà kí ó lè dé, ti èmi àti èyin yóò wà bíi tọkọtaya. Mo rò pé ọ̀rọ̀ tí mo sọ yìí kò ní bí yín nínú. Bí ó bá sì bí yín nínú mo bẹ̀ yín kí ẹ dáríjì mí, kíi ẹ fi ara yín sí ipò mi. Mo sì tún bẹ̀ yín pé bí ó ti wù kí ó rí, kí ẹ má ṣàì fèsì ìwé yìí, kí ẹ sì jọ̀wọ̀ kí ẹ máṣe jẹ́ kí èsì náà pẹ́ rárá. Ẹ bá mi kí gbogbo àwọn ará ilé yín, ói dùn mi pé n kò lè rí bàbá ní ijọ́sí, kí ẹ kí wọn fún mi. Ó dàbí ẹni pé ẹ wí fún mi pé àbúrò yín kan lọ sí ìdálẹ̀ ní ọjọ́sí, o ti dé bí? Bí ó bá ti dé kí ẹ bá mi kí i dáadáa. Ó dìgbà díẹ̀ ná, N o máa retí ìwé yín Èmi ni tiyín títí mo fi máa kú Ìrìnkèrindò. Àkíyèsí:- Mo dúpẹ́ ohun ìkọ̀wé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí mi. Báyìí ni mo kọ̀wé ti mo fi ránṣẹ́ sí Ìfẹ́pàtàkì. Ìgbà tí iwin tí mo fi ran sì dé o ní kò rí ààyè kọ̀wé padà ṣùgbọ́n ó fi ẹnu ran òun kí òun sọ fún mi pé òun ó fèsì ní ọjọ́ kejì. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́ láàótọ́ mo rí ìwé rẹ̀, ohun tí o sì kọ ni èyí: “Odò Ìrántí “Ní ìtọ́jú Ẹbọra olókun “ Ọjọ́ kẹrinlélógún oṣu kejìlá “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́wá ọdun ó lé “Méjìléláàdọ́ta lẹ́yìn “Ikú olúwa wa Ìrinkèrindò mi ọ̀wọ́n, Mo dúpẹ́ púpọ̀ fún ìwé rẹ tí mo rí gbà mo sì ka ìwé náà dáadáa. O dùn mi pé n kò lè rí ààyè kọ̀wé lánà-án. Àkókò tí oníṣẹ́ dé, mo ń ṣiṣẹ́ pàtàkì kan fún bàbà mi. Nípa ọ̀rọ̀ tí ẹ bá mi sọ, mo bẹ̀ yín kí ẹ máṣe bínú èsì tí mo fẹ́ fún yín: ọ̀rọ̀ náà kò ní lè rí bẹ́ẹ̀ rárá. Láti ìgbà tí mo ti wà ní kékeré ni mo ti pinnu lọ́kàn mi pé nkò ni ní ọkọ títí ọjọ́ ayé mi. Bí ó bá jẹ́ pé mo ti fẹ́ ní ọkọ ni, mo rò pé n ba tilẹ̀ ti di ẹni ti ń bímọ nísisì yìí, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ okùnrin ló ti yọ mi lẹ́nu sẹ́yìn pée ki n fẹ́ àwọn tí mo kọ̀ fún wọn. Ìgbà tí mo rí yín ní ìjọ́sí, àánú yín ṣe mi irú ipò tí ẹ wà, òun ni mo ssì fi ṣe aájò yín, àti pàápàá kìí pẹ́ ki n tó mọ̀ bí ìwà ènìyàn bá ti rí, rírí tí mo ti ri yín ni mo ti mọ̀ pé ènìyàn dáadáa ni yín. Nítorí náà, Ìrìnkèrindò, ẹ jẹ́ kí á kúkú jọ máa ṣiré wa bí a ti ń ṣe é lọ, kí a má fi ti ọkọ àti aya sí. Ẹ̀yin náà kò ri i pé ó dára bẹ́ẹ̀ dan? Ẹ ó rí àkàṣù ẹ̀kọ mẹ́fà tí mo fi ránṣẹ́ sí yìn, mo sì fi mọ́ìnmọ́ín mẹ́fà tí ẹ o fi jẹ wọn sii. Àwọn ọ̀rẹ́ mi kí yìn o, àti pàápàá èyí ti ẹ̀ ń gbúròó tí èmi rẹ̀ jọ ń rẹ́rìn-ín ní apá ọ̀nà ilé wa ní ijọ́sí, tàbí ẹ kò rántí mọ́? Ẹ bámi kí àwọn ọ̀rẹ́ yín dáadáa, Mo dúró níhìn-ín Èmi ni tiyín ní tòótọ́ Ìfẹ́pàtàkì Nígbà tí mo ka ìwé yìí tán mo mí kanlẹ̀, inú mi bàjẹ́ ó rí rúdurùdu, n kò mo òsì tí n bá fún ẹni tí ó rán wá, mo wí fún un pé kí ó máa lọ, n ó fi èsì r��nṣẹ́ nígbà tí ó bá ṣe. Nígbà tí ó lọ tán mo fi ìwé náà han àwọn ọ̀rẹ́ mi, nígbà tí wọ́n yẹ̀ ẹ́ wo, wọ́n ní ìwé náà kò burú, wọ́n ní ki n máa kọ̀wé síi dáadáa ki n mo sì ṣe yọ ọ́ lẹ́nu nípa ọ̀ràn náà mọ́, wọ́n ní ó lè fẹ́ mi nígbà tí ó ba ṣe bí mo bá lè mú sùúrù díẹ̀ nítorí bí a bá ti ṣe ń kọ̀wé sí ara wa ni a ó túbọ̀ máa fẹ́ràn ara wa àti pé nígbà tí ìwé bá pọ̀ díẹ̀ láàrin ara wa mo lè tún rọra bá ẹnu lu ọ̀rọ̀ náà lẹ́ẹ̀kan sí i. Mo gba ìmọ̀ràn wọn mo tẹ̀lé e dáadáa. A bẹ̀rẹ̀ síí kọ̀wé sí ara wa à ń fi nǹkan ránṣẹ́ sí ara wa pẹ̀lú, bí mo bá pa ẹran èmi a fi ránṣẹ́ sí i, bí òun náà bá ṣe ọbẹ̀ á bú ránṣẹ́ sí mi. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nínú ìwé mi mo máa ń sọ̀rọ̀ kan ibẹ̀ ṣùgbọ́n kò ni fèsì apa ibi tí moti sọ̀rọ̀ náà nígbà tí o bá máa fún mi ni èsì. Ṣùgbọ́n èmi pàápàá mọ̀ pé ó túbọ̀ ń fẹ́ràn mí sí i. Ọ̀rọ̀ náà kọ́ mi lọ́gbọ́n púpọ̀, lọ́nà kín-ín-ní, o fì hàn mi pé bí ènìyàn bá rí nǹkan dáadáa kò yẹ kí olúwarẹ̀ sọ ọ́, o sì yẹ kí ọkùnrin ronú jinlẹ̀ kí o tó máa sọ irú ẹni tí obìnrin kán jẹ́, nítorí ni ọjọ́ tí mo kọ́ rí ọmọbìnrin náà léti’odò, tí kò pẹ́ púpọ̀ tí ó bèèrè pé ṣe mo ní ìyàwó tàbí n kò ní, mo ṣebí ó fẹ́ ki n fẹ́ òun ni, ṣùgbọ́n ìgbà tí mo tó wá kọ ẹnu nǹkan bẹ́ẹ̀ sí i ni mo tó mọ̀ pé ọ̀ràn kò rí bí èmi ti ń ròó. Lọ́nà kejì, mo ri pé ìfẹ́ kìí ṣe ọ̀ràn ẹnikan, ọ̀ràn ẹniméjì ni. Kì í ṣe pé kí ọkùnrin kan máa fẹ́ràn obìnrin kan, kí ó máa fẹ́ràn obìnrin yìí, kí òun nìkan máa fẹ́ràn rẹ̀ láì jẹ́ pé onítọ̀hún náà fi ìfẹ́ hàn sí òun ni ìfẹ́ fi lè dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé kí obìnrin maa fẹ́ràn ọkùnrin kí òun nìkan máa fẹ́ràn ọkùnrin sá láì jẹ́ pé ọkùnrin náà fi ìfẹ́ tirẹ̀ hàn sii ni ìfẹ́ fi lè gòkè rárá. Bí mo ti fẹ́ràn obìnrin náà ni òun náà ń fẹ́ràn mi. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ kan báyìí, bí mo ti jí, Ewe-ẹ̀yẹ ni mo kọ́ rí, ó wọ ṣòkòtò tí kò pupa tí kò sì funfun tí àwọ̀ rẹ̀ jẹ́ búlù èyí ni pé o fi ara jọ aṣọ aláró. Nígbà tí èmi náà wo inú àpò mi, mo wọ ṣòkòtò kan tí ó jẹ́ ti baba mi tẹ́lẹ̀ tí mo jogún lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọ̀ rẹ̀ náà ni, ti búlúù ni - nígbà tí òárún là, àwọ̀ sánmọ̀ mọ́lẹ̀ kedere, àwọ̀ ojú ọ̀run sì jẹ́ búlúù. Lọ́jọ́ náà gan-an ni mo ń retí ìwé láti ọ̀dọ̀ Ìfẹ́pàtàkì, nígbà tí àbúrò rẹ̀ tí ó rán sí mi sì dé ẹ̀wù búlùú ló wọ̀, ìgbà tí o tún fi ìwé lé mi lọ́wọ́, àpò ìwé ti wọ́n fi i sí nínú búlùú ni àwọ̀ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àpò ìwé funfun ni ó máa ń lò fi kọ̀wé sí mi, àmì ìfẹ́ sì ni àwọ̀ búlùú jẹ́. Nítorí náà mo já ìwé náà ni wéré-wéré, ìgbàtí mo sì rí ìwé yìí búlùú tún ni àwọ̀ rẹ̀. Nígbà tí mo kà á, ohun tí mo bá níbẹ̀ ni èyí: “Odò Ìrántí “Ní ìtọ́jú Ẹbọra olókun “ Ọjọ́ kẹẹ́dógún oṣu kejìlá “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́wá ọdun ó lé “Méjìléláàdọ́ta lẹ́yìn Ikú olúwa wa Ìrinkèrindò Tèmi, Nínú ìwé rẹ tí o kọ gbẹ̀yìn, mo rí i pé o tún sọ̀rọ̀ kan ti wí pé kí ó le ṣeéṣe kí a jọ máa gbé pọ̀ níjọ́ mìíràn. Mo rò pé mo ti sọ fún ọ ní ijọ́sí bí ó ti jẹ́ pé mo ti pinnu láti ìgbà èwe mi wá pé n kò ní fẹ́ ẹnikẹ́ni ṣùgban wí pe n o dúró ní tèmi láì ni ọkọ ni, ṣùgbọ́n nígbà tí mo wo aàpọn gbogbo tí o ti ń ṣe lórí mi láti ọjọ́ tí a ti jọ ń bọ̀ yìí, mo rii pé kò ní dára bí mo bá kọ̀ jalẹ̀, nítorí kò yẹ kí nǹkan kan wà tí mo lè fi dù ọ́. Nítorí náà mo rò pé ọ̀rọ̀ náà yóò ṣe é ṣe. Mo ti wí fún bàbá mi, o sì ti gbà bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ó ní kí o ránṣẹ́ wá kí àwọn ará ilé rẹ wá tọrọ mi lọ́wọ́ òun, nígbà tí ó wí báyìí, mo sọ fún un pé ọ̀nà ìrìnàjò sí ÒKè Ìrònù ni o wà àti wí pé àwọn ara ilé rẹ kò ní lè wá, kò kọ́ gbà, ṣùgbọ́n, mo lọ bá ẹ̀gbọ́n mi àgbà, àbúrò rẹ̀, ó sì ti báa sọ ọ́ pe kí wọ́n má wá mọ́, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ pé kí o kọ̀wé sí bàbá mi, Nítorí náà, ọwọ́ rẹ ló kù sí nísisì yìí, kí o tètè kọ̀wé sí bàbá mi o. Kí o kọ̀wé náà wéré-wéré bí o bá ti rí ìwé mì yìí. Ọmọ tí mo rán wá yìí, àbúrò mi ni, ọmọ ìyá mi ní sàì jíṣẹ́ fún mi. Bí ọ̀rọ̀ kan bá wà tí o kò fẹ́ kọ sí ìwé, kí o wí fún àbúrò mi yìí kí ó wá sọ fún mi. Ọ̀rọ̀ mi kò jù báyìí lọ, Èmi ni tìrẹ Ìfẹ́pàtàkì. Báyìí ni ìwé ọmọ náà lọ, n kò tilẹ̀ mọ̀ bí inú mi ti rí mọ́ nígbà tí mo gbà á, inú mi dùn tó bẹ́ẹ̀ tí n kò mọ nǹkan ti ń bá ṣe lẹ́sẹ̀ kan náà. Mo rán àbúrò rẹ̀ padà, mo sì yára kọ̀wé kékeré kan wí pé inú mi ti dùn tó bẹ́ẹ̀ ti n kòí tíì lè fèsì nígbà náà, àti pé Ìfẹ́pàtàkì máa retí ìwé mi náà lóòótọ́. Nígbà tí àbúrò rẹ lọ tán tí a bẹ̀rẹ̀ síí sọ̀rọ̀ ọmọ náà kò si ẹnìkan ṣoṣo nínú wa tí kò gbádùn rẹ. Olúkúlùkù àwọn ẹnìkejì mi tí wọn ti mọ bí ọ̀ràn ìfẹ́ wa ti ń lọ sì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí yín ìn. Mo kọ̀wé tí ó níláárí sí i, mo sì kọ sí bàbá rẹ̀ pẹ̀lú, bàbá rẹ̀ fèsì o ní bí ọmọ òun bá ti wí pé mo wu òun ó parí, kí a má fẹ́ ara wa. Ní ọjọ́ tí mo lọ bẹ̀ ẹ́ wo tí mo rí ilé rẹ̀ àti irú ipò ọlá tí ó wà ó yà mi lẹ́nu pé irú ọlọ́lá bẹ́ẹ̀ lè wí pé òun máa fẹ́ èmi ọdẹ. Iwin inú fìlà Fìlásayépọ̀ fẹ́ràn mi dáadáa nítorí ẹ̀jẹ̀ níí mu, bí mo bá sì ti ń pa ẹran ni mo ń fún un mu o sì ti gbà pe òun a máa gbé mi lọ sí ọdọ ọmọ náà nígbàkígbà tí o bá wù mi, Èmi náà sì ń lọ síbẹ̀ lemọ́ lemọ́. Ìfẹ́pàtàkì nílá rí púpọ̀, àpẹẹrẹ pàtàkì ni ó jẹ́ fún àwọn ọmọge. Titi a fi gbá ara wa ní ìyàwó, kò hùwà àbòsí kan sí mi rí, kò wí pé ki n wa kí n dé ibẹ̀ ki n má báa, kò wí pé kí a pàdé ní ibì kan kí n dé ọ̀hún ki n ma rí i, kò yẹ àéhùn lọ́jọ̀ kan ṣoṣo rí, bí mo bá dé ilé wọn ẹni ti ó bá tọ́ kí n kí tí n kò tíì kìí, a tọka rẹ̀ sí mi, bí àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ kan nípa mi á wí fún mi, bí ojú mi yípadà díẹ̀ kínún, ó ti mọ̀, kò tú àṣírí mi rí, àfi bí ó bò ó, ọ̀rọ̀ tí mo bá fi pamọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, kò jẹ́ wí i fún ẹnikẹ́ni, ènìyàn rí i gbẹ́kẹ̀lé. Ki n má fa ọ̀rọ̀ náà gùn lọ títí, kò pẹ́ púpọ̀ tí mo ti ń lọ sí ile rẹ̀ tí a dá ọjọ́ ìgbéyàwó wa. Nígbà tí ìgbéyàwó ku ọ̀la, díẹ̀ nínú awa tí à ń lọ sí òké Ìrònù lọ sí ilé ọ̀gbẹ́ni Ajébúlẹ̀ tí o ń gbé etí odò Ìrántí tí ó jẹ́ àná mi. Awa tí a lọ tó mẹ́rìnlélógùn ṣùgbọ́n àwọn tí a fi sí ibùdó wà ní ojú ọ̀nà òkè Ìrònù tó àádọ́jọ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló bá wa jáde ní ìlú àwọn Alásejù tí ó jẹ́ pé wọn kò bá wa ti ilé lọ. Nígbà tí ó di ọjọ̀ ìgbéyàwó gan-an a wọ asọ tí a o mu lọ sí ibi oúnjẹ tán, agogo lù ní agogo mẹ́jọ àbọ̀ pé kí a lọ̀ jẹun. Onírúu’rú oúnjẹ ni wọn fi fún wa jẹ, nítorí onírúúrú ẹ̀dá alààyè ni ó wá sí ibi ìgbéyàwó náà. Àwọn iwin wá ní onírúúrú tiwọn. Àwọn ẹranko wà lọ́tọ̀. Ajá ni o n ṣe ìtọ́jú àwọn ẹranko nítorí òun ti gbé à[rin àwọn ènìyàn rí, ológbò ni o ń ran ajá lọ́wọ́. Ohun tí ó jẹ ìyanu jùlọ pátápátá ni àkókò yìí ni àláàfíà tí o wà láàrin àwọn ẹ̀dá alà[[e, ìrẹ́pọ̀ irú èyí t;i ẹnikẹ́ni kò pìtàn rí. kìnìhún pẹ̀lú àgbọ̀rín n fi ọwọ́ kó ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ń siré kiri, ológbò àti èkúté ń ṣe ọ̀rẹ́ tí a ń yọ̀ pé àwọn fẹ́ di àna. Ibi tí àwọn ẹyẹ wà dára gidgidi àti àṣádi àti àwọn ẹyẹ kéékèèké gbogbo ni wọ́n jọ ń jókòó tí ọ̀kan kò wá ìpalára èkejì. Nínú àwọn tí o wá ni ejò wà, pẹ̀lú ayọ̀ ni wọn fi ń bá wa gbé tó bẹ́l ti n kì í fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn nítorí ènìyàn ń fi ọwọ́ ba ọká ní ìrù láìjẹ́ pé ó ń buni ṣan. Àkeekèé jókòó láàrin àwọn kòkòrò, ó ti fi oró pamọ́ sílé. Ọ̀pọ̀lọ́ àti akàn tí o sì wá gẹ́gẹ́ bí aṣojú àwọn ẹja hùwà ọmọlúàbí gan-an. Nígbà tí a jẹun tán, mo ṣe àkíyàsí pé gbogbo ẹni tí ó jẹun ni ó yó pátápátá, ṣùgbọ́n oúnjẹ kò ṣẹ́kù sínú àwo ẹnikẹ́ni. Ètò ìyàwó náà jẹ́ ìyanu, kò sí pé ẹnìkan ń pẹ́ lẹ́yìn, kò sí pé ẹnìkan ń pariwo, kò sí pé ẹ̀rún oúnjẹ kan ṣoṣo ń ba ilẹ̀ jẹ́. Ṣíbbí fàdákà ni àwa tí a jẹ́ ènìyàn àti àwọn tí ó jẹ́ iwin lò, àwo fàdákà ni a fi jẹun, ife fàdákà ni a sì fi mu omi. Gbogbo àwọn ẹranko àti ẹyẹ tí ó wá sí ibẹ�� ni ó lè sọ̀rọ̀ kí ènìyàn gbọ́. Nínú iyààrá kan lọ́tọ̀ ni àwọn èèrà wà, níbẹ̀ ni wọ́n ti ń jẹun, ìgbà tí mo lọ kí àwọn èèrà, mo gbádùn wọn, wọ́n sọ̀rọ̀ dáadáa ohùn wọn rọra ń dún bí fèrè olòhùn goor, wọn kò bu ni jẹ mọ́, èyí tí o ni oró ti fi oró pamọ́ sílé, ìgbà tí àwọn ejò sì wá síbẹ̀ wá kí wọn, wọ́n jọ gbádùn ara wọn lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ìgbà tí mo rí ejò òjòlá kan lẹ́yìn èyí, ó ròyìn bí àwọn àti èèrà ti gbádùn tó, bẹ́ẹ̀ ni àkókò yìí, ọ̀pọ̀lọ́ àti ejò jọ ń fi ọwọ́ kọ́ ọwọ́ rìn kiri ni, A! Àkókò àlàáfíà gbáà, n kò lè gbàgbé ọjọ́ ìgbéyàwó yìí bi ayé yípadà tó bẹ́ẹ̀ ti màlúù ń lóyún ewúrẹ́ tí ológbò ń bí àkùkọ. Nígbà tí a máa wọ aṣọ ìgbéyàwó, àwọn iwin ni wọn fún gbogbo wa ní aṣọ, wọ́n fún mi ni ẹ̀wù góòlù, ṣòkòtò góòlù, fìlà góòlù, àti bàtà góòlù gbogbo ohun tí mo fi sí ara jẹ́ góòlù pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni ó yà mi lẹ́nu pé agbádá àti dàńṣíkí góòlù yìí kò ba mi lẹ́rù rárá, àti pé aṣọ náà kò wúwo ju ẹ̀wù lásán lọ. Ẹwu tí àwọn ẹnìkejì mi yàtọ̀ sí tèmi, aṣọ ti ẹ̀wù wọn kìí ṣe góòlù ṣùgbọ́n wọ́n fi góòlù ṣe ọnà síi lára. Ìgbà tí a máa lọ sí ibi ìgbéyàwó gan-an, àwọn iwin wọ̀n-ọnnì wa sínú ilé ńlá tí mò ń gbá tí bàbá ìyàwó mi fún mi, wọ́n mú èmi àti àwọn ẹnìkejì mi lọ sí ibi kan báyìí tí ó tẹ́jú pẹrẹsẹ, aṣọ tí wọn fi fàdákà ṣe ni wọ́n tẹ́ láti ile mi lọ sí ibi tí à ń sọ̀rọ̀ yìí, wọ́n gbé mi gun ẹṣin tí wọ́n fi díámọ́ǹdì ṣe ọ̀ṣọ́ sí lara jìngbìnnì kanlẹ̀, wọ́n sì to àwọn arẹwà ọkùnrin àti obìnrin sí etí ọ̀nà lọ ní apá ọ̀tún àti apá òsì. Àwọn wọ̀nyí wọ aṣọ tí ó ń dán bí dígí tí n kọ mọ̀nàmọ̀nà bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, àwọn ẹnìkejì mi náà gun ẹsin tẹ̀lé mi lẹ́yìn, bí a ti ń kọjá ni àwọn tí ó dúró sí e’ti ọ̀nà wọ̀n-nnì bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin, ohùn wọn dàbí ẹni pé ẹnìkan kọ́ ọ̀kẹ́ àímoye ẹyẹ ni orin kan náà ti ohìun wọn ń dún gooro. Ibi tí ó tẹ́jú pẹrẹsẹ báyìí ni wọ́n mú wa lọ, ó tẹ́jú tí n kòi rí ibi ti ó tẹ́jú tó bẹ́ẹ̀ rí, ó gùn tó ogún ìsẹ́jú ní ìbú, ó sì tó bẹ́ẹ̀ ní òró, bẹ́ẹ̀ bi aṣọ àrán tí àwọ̀ rẹ̀ jẹ́ búùlù tí ó sì nípọn tó ẹsẹ̀ bàtà kan ni wọ́n tẹ́ tí ó bo gbogbo ibẹ̀ po. Ìgbà tí a dé ibẹ̀ ńlá kan wà báyìí, orí àga yìí ni mo jókòó lé àwọn ènìyàn mi náà sì jókòó lé àga tí o tẹ̀lé tèmi. Bí mo ti fi ìdí balẹ̀ lórí àga ni ariwo ta pé ìyàwó mi ń bọ̀, bí o ti n bọ̀ ni a sì ń gbọ́ tí wọn ń yìnbọn lẹ́ẹ́kọ̀ọ̀kan. Àwọn tí o ń lu ìlù tí wọn ń jó ni wọ́n wà níwájú pátápátá. Lẹ́yìn àwọn onílù wọ̀n-ọnnì ni àwọn onífèrè dé tí wọ́n wọ aṣọ kan náà, tí wọ́n tò ní méjì méjì bí wọ́n ti ń gbé ẹsẹ pọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Lẹ́yìn àwọn onífèrè ni a rí àwọn ọmọdé tí wọn tó bí ọgaọ́ta tí wọ́n wọ aṣọ òkúta olówó iyebíye, lẹ́yìn àwọn wọnyí sì ni ogunlọ́gọ̀ wúndíá tí wọ́n wọ aṣọ aláràbarà dé. Lẹ́yìn náà ni a rí obìnrin mẹ́ta àti ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n dúró ni apá ọ̀tún àti apá òsì tí wọn ọmọ ìyà ìyàwó mi. Lyìn èyì wàyí ni a ri ìyàwo mi nínú kẹkẹ góòlù tí ẹṣin mẹ́rìndínlógún n fà, àwọn ẹsin wọ̀n-nnì kún fún ohun ọ̀sọ̀ láti òkè dé ìsàlẹ̀, ní apá ọ̀tún àti apá òsì kẹ̀kẹ̀ ìyàwó mi yìí ni kẹ̀kẹ́ bẹ́ẹ̀ méjì tún wà tí ó jẹ́ ti góòlù tí ẹsinn mẹ́rìndínlógún mẹ́rìndínlógún tún ń wọ́, ẹ̀gbọ́n ìyàwó mi ọkùnrin lo wà nínú méjéèjì tí wọ́n jẹ́ ìbátan rẹ̀. Ìyàwó mi ró aṣọ díámọ́ǹdì, ó wé gèlè díámọ́ńdì pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run ni díámọ́ǹdì, máa n dán yinrinyinrin. Kẹ̀kẹ́ bàbá ìyàwó mi lo tẹ̀lé ti ìyàwó mi, kẹ̀kẹ́ fàdákà ni, òun náà lẹ́wà gidigidi. Ìyá ìyàwó jókòósílé o ń tọ́jú oúnjẹ. Báyìí ni gbogbo nǹkan rí, iwin kan báyìí báyìí tí orí rẹ̀ sì ti hu ewú pátápátá tí ó funfun láú ni wọ́n pè kí ó wa ṣe ìgbéyàwó náà fún wa. Ìgbà tí a kọrin dídún tán tí gbogbo ẹni ti ó wá jókòó tán, iwin náà ní kí èmi àti ìyàwó mi bọ́ síwájú a sì lọ, lẹ́yìn tí o sì ti béèrè lọ́wọ́ mi lójù gbogbo aye bí mo bá pinnu láti fẹ́ obìnrin náà, ti mo ti jẹ́wọ́ tán ó ni, ki n máa wí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tẹ̀lé oun: Èmi Ìrinkèrindò, ọmọ Ìfẹ́dayépọ̀, ọmọ ènìyàn, ti n gbé Ilé- Alárìnkiri, ti ń lọ sí òkè Ìrònù, nínú igbó Elegbeje, gba Ìfẹ́pàtàkì, ọmọ Ajédùbúlẹ̀, ti ń gbé odó Ìrántí, àbúrò Olókun tí í ṣe alákòóso omi. Mo sì ṣe ìlérí, níwájú ènìyàn, àti níwájú iwin, níwájú ẹ̀mí ti à ń rí, àti níwájú èyí tí a kò rí, níwájú ejò àti níwájú ẹranko, níwájú ẹyẹ àti níwájú kòkòrò, níwájú ọ̀pọ̀lọ́ àti níwájú akàn, wí pe: bí mo ti fẹ́ ọmọ náà yìí, nn kò níi jẹ́ kí ìyà jẹ ẹ́, n kò ní jẹ́ kí ebí pa a, n ó sì máa ṣe aájò rẹ̀ bí ó ti yẹ. Bí ara rẹ̀ kò bá le, n ó bá a wá òógùn si i, bí n kò bá mọ òògùn àìsàn náà, n ó wí fún àwọn tí ó bà mọ̀ ọ́, kí wọ́n ṣe é fún mi. Kì í ṣe eléyìí’nìkan. Mo níláti mọ̀ pé, aájò tèmi kò bá le, n o fi ọwọ́ bàá lára, láti mọ̀ bí ara rẹ̀ bá ti gbóná sí, n ó béèrè bí ìyàwó mi ti ń gbádùn sí, n ó kìí láti fi hàn pé mo mọ iyì rẹ̀, bí òtútù bá ń pa á, n o mú aṣọ mìíràn, n ó dà á bò ó lára, n o béèrè ohun tí o ń fẹ́ jẹ, bí ó bá sì ti sọ fún mi, n ó yára ránṣẹ́ kí wọ́n máa wá a, n kò ní lọ sí òde. Ki n máa siré lọ́hùn-ún, kí ó sì dàbí ẹni pé n kò bìkótà fún ìyàwó mi, nítorí aláìmọ̀kan ni ènìyàn náà, tí ara ìyàwó rẹ̀ kò dá nílé, tí ó bá òde ẹmu lọ, tí o ń rẹ́rìn-ín lọ́hùn-ún bí ẹni pé kò sí nnkan kan. Mo sì tún ṣe ìlérí pẹ̀lú pé kò sí ohunkóhun tí obìnrin yìí lè ṣe, tí n ó fi gbé ọwọ mi sókè lùú, ẹni tí ó bá lu ìyàwó rẹ̀, olúwarẹ̀ lu ohun ẹlẹgẹ Olódùmarè, ó mú ara rẹ̀ kúrò ni ipò ènìyàn, ó fi ara rẹ̀ sí ipò ajá tí ó ní dìgbọ̀lugi. N ó máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ara ilé ìyàwó mi, ẹni tí o ṣe àfojúdi sí àwọn obi aya rẹ̀ ti fi ara rẹ̀ gégùn-ún, ẹni tí o fi àna rẹ̀ bu ti sọ ara rẹ̀ di ẹni èpè. Bí ìyàwó mi bá sọ̀rọ̀ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn mi, n ó fún un ní èsí tí ó yẹ. Bí ó bá ń fẹ́ ìmọ̀ràn nípa nǹkan kan, n o fún un nì ìmọ̀ràn tí mo bá mọ̀, n kò ní sọ ilé wa di ilé ìbànújẹ́, ki n máa rojú kórókóró kiri, ki n máa dákẹ́ dúduudu. Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, n ó máa bá ìyàwó mi ṣe àwàdà, n ó máa bá a rẹ́rìn-ín, n ó máa báa ṣiré titi ọjọ́ ayé mi. Mo tún ṣe ìlérí níwájú gbogbo yín, pé n ó kìlẹ̀ fún ojú mi, n kò ní jẹ́ kí ojú kòkòrò wọ ibẹ̀, bí ìyàwó mi ti ń wù mí tẹ́lẹ̀, ni yóòo máa wù mí títí láéláé. Nínú àìsàn, yóò máa wù mí; nínú ìlera yóò máa wùu mí; ìgbà tí ó bá lóyún, tí ikùn rẹ̀ bà yọ bọ̀ǹbọ̀, tí ètè rẹ gbẹ, tí ara rẹ̀ funfun, yóò máa wù mí síbẹ̀ náà ni. N kò ní jẹ́ kí ìyàwó mi tẹ́ láàrin ẹgbẹ́, n kò sì ni fii sílẹ̀ kí ojú máa pọ́n ọn. Èmi sì mọ̀ pé, ọmọ yìí kìí ṣe ọmo ìyá mi, bí ó bá ṣẹ́ mi, mo níláti bomi ṣùúrrù mu, bí mo bá bínú díẹ̀, dandan ni kí n tètè ronú padà ki n fi ẹ̀rín lé ìbínú lọ ní ilé wa. Mo tún ṣe ilérí lónìí pé, bí ó ti wù tí inú bí mi tó, ọ̀rọ̀ burúkú kò ní ti ẹnu mi jáde si i. Mo mọ̀ láti òní lọ pé, ìyàwó yìí lè lọ bímọ fún mi, bí ó bá bímọ fún mi, ki ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọba ki ń tọ́jú ọmọ tí o fi jínkí mi. Mo tún mọ̀ bákan náà pé, ìyàwọ mi yìí lè ṣàì bímọ fún mi, bí èyí bá jẹ́ ìpín mi, n kò gbọdọ̀ jẹ́ kí èyí ba àlàáfíà ilé wa jẹ. Ó jẹ́ àṣà tí ó burú jùlọ lọ́pọ̀lọpọ̀, láàrin àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, pé kí ẹni tí kò bímọ, rò pé ayé òun ti bàyẹ́, kí ó rrò pé fi òun ti parí, kí ó máa kábàámọ̀ pé, kí ni òun wá sí ayé ṣe, ènìyàn lè wà ní àìlọ́mọ, kí o ṣe ayé ní rereju ọlọ́mọ lọ, ènìyàn lè bímọ, kí o bí ìjàngbọ̀n sílẹ̀, kí o fi ọmọ rẹ̀ ṣe ayé ní ibi. Lórí gbogbo ìwọ̀nyí, èmi, Ìrìnkèrindò, tí o di ọkọ Ìfẹ́pàtàkì lónìí, bẹ gbogbo yín, kí ẹ bá mi gbádùrà pé ẹrù ńlá tí mó tẹ́ orí gbà lónìí, kí Olódùmarè bá mi gbé e; kí Ọlọ́run bá mig bé e; kí Ẹlẹ́dàá mi bá mi gbé e, kí ọba Àìkú bá mi gbé e, kí ọba Àìrí bá mi gbé e, kí ọlọ́jọ́ òní bá mi gbé e, kí ọba Alèwílèṣe bá mi gbé è, kí Alákòóso ayé àti Alákòóso ọ̀run bá mi gbé e, kí àwọn ogun ọ̀run sì máa bá mi gbé e titi láéláé. Nítorí náà, ìyàwó mi, Ìfẹ́p��tàkì, mú ọwọ́ rẹ wá, èmi, Ìrìnkèrindò fi òrùka díámọ́ǹdì yìí, bá ọ dá májẹ̀mú wí pé láti òní lọ, mo di tìrẹ; wí pé, láti òní lọ, o di tèmi; wí pé láti òní lọ, ayọ̀ rẹ ni yóò jẹ́ ayọ̀ mi; ìbànújẹ́ rẹ ni yóò jẹ́ ìbànújẹ́ mi; àwọn ara ilé rẹ yóò sì jẹ́ ará ilé mi. Àkókò náà dé wàyí, tí ẹn8i méjì pa ara pọ lójú gbogbo ayé tí wọ́n di ọkan ṣoṣo. Báyìí ni mo sọ lójú gbogbo àwọn tí o wá sí ibi ìgbéyàwó mi. Nígbà tí mo ka ìwọ̀nyí tẹ̀lé iwin tí o ṣe ìgbéyàwó náà fún ni tán. Ó kọjú sí ìyàwó mi, o ní kí o tún maa wí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tẹ̀lé òun; Èmi, Ìfẹ́pàtàkì, ọmọ Ajédùbúlẹ̀, iwin, tí ń gbé odò Ìránti’, àbúrò olókun, ti i ṣe alákòóso omi, gba Ìrìnkèrìndò, ọmọ Ìfẹ́dayépọ̀, ọmọ ènìyàn, ti ń gbé ilú Alárìnkiri, tí o ń lọ sí òkè Ìrònù, ti ń bẹ nínú Igbó Elégbèjè, bí ọkọ mi. Mo sì ṣe ìlérí, níwájù ènìyàn, àti níwájú iwin níwájú ẹ̀mí tí a rí àti èyí tí a kò rí, níwájú ejó àti níwájú ẹranko, níwájú ẹyẹ àti níwájú kòkòrò, níwájú ọ̀pọ̀lọ́ àti níwájú akán wí pé: bí mo ti gbà á yìí, mo mọ pé kìí ṣe ǹnkan ṣiré ṣiré, nǹkan pàtàkì ni. Láti òní lọ, mo fi ilé ìyá mi sílẹ̀ , mo di ìyá sí ilé tèmi. Mo níláti kìlọ̀ fún ẹnu mi, àṣíírí ilé wa, n kò gbọdọ̀ tú u fún ẹnikẹ́ni, ọ̀rọ̀ tí baálé mi bá fi sí mi lọ́wọ́, n kò gbọdọ̀ gbé e lọ sílé ìyá mi. Mo sì ṣe ìlérí lónìí pé, bí àyípadà bá dé, tí ó di pé báálé kò rí owó jẹun mọ́, ìfẹ́ mi yóò dúró bí tí àtíjọ́ ni, bí àyípadà bá dé, ti ara baálé kò le, ìfẹ́ mi kò ní ṣákì, ń ó máa tọ́jú rẹ̀ náà ni, bí àyípadà ba dé, ti baálé mi túbọ̀ ń dágbà, tí ẹwà eẹ̀ ń dínkù, tí kò le ṣe fáàrí bi ti àtijọ́ mọ́, ìfẹ́ mi kò ní yípadà si i. Mo tún ṣe ìlérí pé, n kò ní í jẹ́ ẹelẹnu méjì bí i fèrè, kí n wí pé mò ń lọ sí odò, kí wọ́n bá mi ni oko, ki n pé ẹnìkan ní ará ilé mi, ki wọ́n báa pá kò bá mi tan. N ó tọ́jú ilé wa, n o tọ́jú owó ilé wa, n kò ní ná ìnákùná, ki n di ẹni ti ń tú owó baálé mi ká. Oúnjẹ ṣe pàtàkì nínú iṣẹ́ mi, n ó máa wá a lákòókò, n ó máa ṣè é dáadáa pẹ̀lú, n o ṣe ìtọ́jú baálé mi tó bí ó ti yẹ bí ara rẹ̀ kò bá le, nítorí mo mọ̀ pé, ègún ni fún obìnrin náà, tí ara baálé rẹ̀ kò dá, tí ó mú aṣọ tí baálé rẹ̀ rà fún un, tí o ṣiré bá òde lọ; ègún ni fún obìnrin náà, tí ó ti torí pé ìjà dé tí o ń sọ̀rọ̀ tí òun àti ọkọ rẹ̀ ti fi ṣe ìpamọ́ sí ìta. Ìwà burúkú ni fún obìnrin náà, tí baálé rẹ̀ fún ni owó oúnjẹ, tí kó ṣe oúnjẹ, tí ó bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ. Mo mọ̀ láti òrú lọpé ọ̀rọ̀ rere a máa yọ obi lápò; ọ̀rọ̀ burúkú a máa yọ ọfa lápá, nítorí náà bí mo bá sẹ baálé mi, tí ó di pé o ń bínú, n ó sọ̀rọ̀ tútù fún un. Mo mọ̀ pé àwọn obìnrin mìíràn, kà á sí ẹ̀tẹ́ pé, kí àwọn tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọkọ àwọn bí àwọnn bá ṣẹ̀ ẹ́, mo sì mọ̀ dájú pé, ara ni irú àwọn bẹ́ẹ̀ fi yàtọ̀ sí ìnàkí, agbárí wọn ti ìnàkí ni. Mo sì mọ̀ pé, iṣẹ́ mi pàtàkì ni la’ti máa kọ́ ìwà baálé mi, ki ń mọ nǹkan tí ó fẹ́ ki ń mọ nǹka tí kò fẹ́, ki n ṣe nǹkan tí o fẹ́, ki ń yàgò fún nǹkan tí kò fẹ́. Ọ̀rọ̀ tí yóò bá ìbínú rẹ̀ pàdé, mo níláti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Oúnjẹ tí kò fẹ́ n kò gbọdọ̀ gbe fún un. Bí ó bá gbàgbé nǹkan sílẹ̀, ki n mú u pamọ́ dè é. Kí ń ṣe ilé mi kí ó mọ́ tóní tóní, kí ohun gbogbo wà ní ètò, ki n sì ṣe iṣẹ́ tí ó bá kàn mi gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, ki n tó lè ṣe ti ara mi. Bí mo bá rí ọmọ bí n o dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè, bí n kò bá sì bí, n kò ní gbé wàhálà ka ara mi láyà, ki n rò pé ayé mi ti bàjẹ́, ki n máa ti ilé dé ilé, ki ń di oníyẹ̀yẹ́ obìnrin, nítorí ó sàn ní ìgbà ẹgbẹ̀rún, kí ènìyàn kú láì ní ọmọ, ju pé kí oluwárẹ̀ di oníyẹ̀yẹ́ sí ààrin ìta. Mo sì ṣe ìlérí pé, n o máa yẹ́ ọkọ mi sí, n ó máa gbé e gẹ̀gẹ̀, n o máa pọ́n ọn, n o máa bu ọ̀wọ̀ fún un, n o máa ṣe fáàrí hàn án, n o máa ró aṣọ mi dáadáa, n o máa wé gèlè mi dáadáa, n o sì máa tọ́jú irun orí mi dáadáa, n o máa wọ bàtà mi dáadáa, n o máa wẹ̀ dáadáa, n o maa run orín mi dáadáa, n ó máa tọ́jú èékán mi dáadáa, bẹ́ẹ̀ ni n ó máa ṣe títí ikú yóò fi yà wá. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni ti yóò wù mi mọ́ nínú àwọn ọkùnrin, rékọjá Ìrìnkèrìndó yìí, ẹni ti ń gbé ilé Alárìnkiri. Báyìí ni ìyàwó mi náà ka tirẹ̀, ìgbà tí wọ́n sì kọrin dídùn tan ní ìsìn ìgbéyàwó náà ti parí ti pári ti a lọ sí ilé ti wọ́n fún wa. Lálẹ́ ọjọ́ náà ni wọ́n mú ìyàwó mi wá bá mi. Ọjọ́ kejì ni a sì tún múra ọ̀nà Òlè Ìrònù. Kì í ṣeiwin inú fìlà Fìlásayépọ̀ ló gbé wa padà, nítorí ọ̀kan nínú àwọn àbúrò ìyàwó mi mọ ọ̀nà àti bá jáq sí ojú ọ̀nà òkè Ìrònú tí kò jìnà púpọ̀ sí odò ìrántí tí a o sì fi lè lọ bá ara àwọn ènìyàn wa yòókù tí kò wá sí ibi ìyàwó. Yóò yà yín lẹ́nu pé títí nǹkan bí oṣù mọ̀rin lẹ́yìn èyí, a kò tíì dé òkè Ìrònù rárá. Ṣùgbọ́n ìdí rẹ̀ ni pé à ń dúró loju ọ̀nà púpọ̀. Odidi oṣù mẹ́ta ni a tilẹ̀ lo ní ìlú kan báyìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìsinmi – àlàáfíà. Ìlú náà dára púpọ̀, àwọn ènìyàn wa lo tilẹ̀ kọ́ dá àbá pé o yẹ kí èmi àti ìyàwó mi dúró díẹ̀ níbẹ̀ kí á gbádùn ara wa. Àwọn náà pàápàá ń fẹ́ simi díẹ̀. Ìgbádùn wa ti pọ̀ ju nǹkan tí ènìyàn lè fi ẹnu sọ ní ìlú Ìsimi – Àlááfìà yìí. Ṣùgbọ́n ó yẹ ki ń fi ẹnu ba ọjọ tí èmi àti ìyàwó mi lọ sí ilé kan ní ìlú náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Òpìtánparapọ̀. Ìtàn sísọ ni iṣẹ́ wọn nínú ilé Òpìtánparapọ̀ ibẹ̀ sì ni ọkùnrin kan báyìí ń gbé tí ó lè sọ ìtàn dé góngó, orúkọ ẹni ti ń jẹ́ Ìtándìran. Jẹ́ kí n sọ ìtàn mẹ́ta fun yín tí a gbọ́ lẹ́nu Ìtándìran. Àwọn ọkùnrin mẹ́ta kan wà orúkọ ẹnì kín-ín-ní a máa jẹ́ Owólayémọ̀, orúkọ ẹ̀kejì ni Afẹ́ayé, ẹ̀kẹta sì ni ọ̀kánjúwàfẹ̀yìntì. Ó wa ṣe, àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta yìí jùmọ̀ ń rìn lọ nínú igbó lọ́jọ́ kan, nítorí ọdẹ ni gbogbo wọn. Bí wọn ti rìn díẹ̀ ni wọ́n rí iwin kan tí o ń sáré bọ̀ tí ó ń ké, ‘Ikú!’ ‘Ikú!’Eléyìí ya àwọn ọddẹ yìí lẹ́nu, wọ́n sì dá iwin náà dáuró, wọ́n bèèrè ohun tí o ń lé e. Ó dáhùn ó ní ikú ni o ń lé òun, o sì tọka sí igi ìrókò kan, ó ní abẹ́ igi náà ni ik;u wà, bí wọ́n bá fẹ́ mọ ikú kí wọ́n lọ sí ìdí ìrókò náà. Kò sí ògbojà tí ó dàbí ọdẹ. Àwọn mẹtẹẹta pinnu láti lọ mọ ikú wọ́n múra o di ìdí ìrókò. Ìgbà tí wọ́n dé ìdí igi náà, wọn kò rí ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n dípò èyí wwọ́n bá àpò owó méjìlá, owo ṣílè gbáà ni. Eléyìí jẹ́ ìyàlẹ̀nu fún wọn pée owó ṣílè ní iwin ń pè ní ikú. Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí wọ́n gbọ́ àkùkọ kan kọ́, wọ́n sì mọ̀ pé etí ìlú kan ni àwọn wà. Ìgbà tí wọ́n ronú nípa bí àwọn ìbá ti ṣe owó yìí, wọ́n pinnu láti kó o lọ nígbà tí ilẹ̀ bá ṣu, nítorí bí àwọn wà, ìgbà tí wọ́n ronú nípa bí àwọn ìbá ti ṣe owó yìí, wọ́n pinnu latí kó o lọ nígbà tí ilẹ̀ bá ṣu, nítorí bí àwọn bá kóo o ní ọ̀sán, wọ́n ó mú àwọn gẹ́gẹ́ bí olè. Ṣùgbọ́n ebí dé, ó pẹ́ tí wọ́n ti ń yí inú igbó kiri wọ́n bá rán ọ̀kan nínú wọn kí ó lọ ra oúnjẹ wá bí o bá ra oúnjẹ tán kí ó ra agbè ẹmu kékeré kan pẹ̀lú, kí àwọn bà mu ú lée orí ounjẹ àwọn. Wọ́n rrán ọ̀kánjúwwàfẹ̀yìntì. Ìgbà tí Ọkánjúwà fẹ́yìntì lọ tán àwọn méjì yòókù bẹ̀rẹ̀ síi ronúbí ìbá ti dùn tó kí á wí pé àwọn méjì péré lorí owó náà, àpò mẹ́fà-mẹ́fà ni àwọn ìbá pín in. Inú àwọn ìbá dún o. Inú báyìí ni àwọn méjéèjì rò, nígbẹ̀yìn ṣá, wọ́n pinnu pé bí ọ̀kánjúwàfẹ̀yìntì bá dé kí a wọ̀ọ̀n yìnbọn pa a. Ọ̀kánjúwàfẹ̀yìntì ní tirẹ̀ náà ń kọ́ kẹ́, bí o ti ń lọ ni òun náà bẹ̀rẹ̀ sisi rọnú bí òun ìbá ti jẹ́ olówó tó kí á wí pé òun nìkan ;òun rí owó yìí. Nígbà tí ó pẹ́ ṣá, ó pinnu bí òun ti ṣe máa ṣe é tí òun lè fi fẹ́ ojú àwọn méjì yìí kù. Ó ra májèlé burúkú kan, kò sí ẹni tí o le gbé májèlé yìí mì tí olúwarẹ̀ lè gba ìṣẹ́jú méjì kí ó tó kú, ó fi èyí sínú ẹmu. Bí Ọ̀kánjúwàfẹ̀yìntì ti dé owólayéemọ̀ gbé ìbọn ttì í ní ookan àyà tí ó yìn ín. Bí ọ̀kánjúwà sì ti ń ta gee, gee lọ ni afẹ́ayé tún ṣá ìbón tirẹ̀ sii, “wì” : Òkú Ọ̀kánjúwàfẹ̀yìntì ní ilẹ̀, ọ̀kájúwà kú. Inú àwọn apànìyàn méjì yìí dun dé inú egungun, wọ́n jókòó jẹ àkàṣù ẹkọ tí Ọ̀kánjúwàfẹ̀yìntì rà tán, wọ́n b���̀rẹ̀ ẹmu mímu. Ṣùgbọ́n kò tó ìṣẹ́jú méjì tí wọ́n mu-ẹmu yìí tí àwọn náà pa ojú dé, wọ́n kú gàlàtì ti owó lọ́rùn. Báyìí ni ojúukòkòrò owó fa ikú bá àwọn ọkùnrin mẹ́ta wọ̀nyí. Nínú gbogbo ikú tí o ń pa ọmọ aráyé, èyí tí ojú-kòkòrò owó ń mú wá kò mọ ní ìba. Eléyìí ni ìtàn kín-ín-ní tí èmi àti ìyàwó mi gbọ́ lẹ́nu Ìtándìran ti ń gbé ilé Òpìtánparapọ̀. Ìtàn náà kún fún ọgbọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀. Báyìí ni ìtàn kejì ṣe lọ: Nígbà kan ẹyẹ ẹ̀gà kan tí ó kọ ilée sí orí àgbàdo kan jáde la’ti kọ̀ wá oúnjẹ, o sì fi àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ilé kí o bà máa gbọ́ ohun tí olóko yyóò wí nípa ọjọ́ ti yóò ya àgbàdo kí àwọn ba lè tètè sálọ. Ìgbà tí ọ̀gà dé lálẹ́ ọjọ́ náà, àwọn ọmọ rẹ̀ wí fún un pé àggbẹ̀ ti rán ọmọ rẹ̀ lọ sí ilé kí ó wí fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kí wọ́n bà wá ba a ya àgbàdo nítorí ọwọ́ òun dí púpọ̀ òun kò rí ààyè ṣiṣẹ́ náà fún ara òun. Ṣùgbọ́n ẹ̀gà bú sí ẹ̀rín ó ni, ‘Ẹ máṣe jẹ́ kíi a lọ níto’ri ìba díẹ̀ ni ọ̀rẹ́ tí ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn, àwọn tí àgbẹ́ ránṣẹ́ sí kò níí wá, níto’ri ènìyàn kò ṣe e gbẹ́kẹ̀lé, ẹ jókòó ẹ̀yín ọmọ mi.’ Lóòótọ́, ni ọjọ́ọ́ kéjì, àwọn ọ̀rẹ́ wọ̀n-ọnnì kò wá, ẹnikẹ́ni kò sí ya àgbàdo. Ní ọjọ́ náà ẹ̀gà tún wá oúnjẹ òòjọ́ lọ, ìgbà tí ó sì dè o béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ bí àgbẹ̀ ti wí, wọ́n wí fún un pé àgbẹ̀ ti ránṣẹ́ sí àwọn ìbátan rẹ̀ kí wọ́n wá ya àgbàdo, ẹ̀gà dáhùn, ẹ̀gà ní, ‘Ẹ jókòó, ẹ máa jẹ, ẹ máa mu, kò sí nǹkan kan, nítorí púpọ̀ nínú àwọn ibátan ọmọ ènìyàn kò ṣé é gbẹ́kẹ̀lé, wọ́n kò ni ya àgbàdo. Lóòótọ́, ilẹ̀ ọjọ́ kejì tún mọ́, àwọn ìbátan wọ̀n-ọnnì tún ṣe onírúurú àwáwí, ẹ̀gà tún múra ó bá ibi iṣẹ́ rẹ̀ lọ. Nígbà tí ó dé ní alẹ́, o béèrè bí olóko ti wí, wọ́n ní olóko ti ránṣẹ́ sí àwọn àna rẹ̀, àwọn tí ó fi ọmọ fún, kí wọ́n wá bá a ya àgbàdo náà. Ẹ̀gà tún rẹ́rìn-ín ó ní, ‘Ẹ jókòó yín jẹ́ ẹ́, wọn kò níí wá, àwọn àna mìíràn dára ṣùgbọ́n púpọ̀ buru ju gbèsè ìdílé lọ.’ Lóòótọ́ ìgbà tí ilẹ̀ tún mọ́ ẹnikeni kò wá. Ẹ̀gà tún bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ. Nígbà tí ó padà dé ní alẹ́ ó tún béèrè bí olóko ti wí. Àwọn ọmọ rẹ̀ sì wí fún un pé olóko pàápàá ti pinnu láti wá ṣíṣẹ́ rẹ̀ ni ọjọ́ kejì. Ẹ̀gà tún bá olóko ti wí. Àwọn ọmọ rẹ̀ sì wí fún un pé olóko pàápàá ti pinnu láti wá ṣisẹ́ rẹ̀ ni ọjọ́ kejì. Ẹ̀gà fa ojú ro, o sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n máa di ẹrù, ó ní, ‘ọwọ́ ẹni kì í tan ni í jẹ, ọkàn ẹni ni àlùfáà ẹni, ní ìwọ̀n bí ọkùnrin náà ti pinnu àti ṣe nǹkan rẹ̀ fún ara rẹ̀, kò ni ṣàì ṣe e.’ Lóòótọ́ bí ilẹ̀ ti ń mọ́ hàì ní ọjọ́ kejì ni àgbẹ̀ ti dé pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, o sì ya àgbàdo rẹ̀ gbogbo. Ṣùgbọ́n kò rí ẹ̀gà mú nítorí ẹ̀gà ti mọ ohun tí ọmọ-ènìyàn lè ṣe. Báyìí ni ìtàn kejì parí nínú ilé Òpìtánparapọ̀. Ìtàn kẹta gùn ju ìtan kejì ti ìṣáájú lọ. Báyìí ni ìtàn náà ti lọ: Ọba ńlá kan wà ní ayé àtijọ́, tí ó ní owó dé góńgó, tí ó bí gbajúmọ̀ lọ̀mọ, tí ìgbèríko rẹ̀ pọ́ bí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn alápàńdẹ̀dẹ̀ tí wọ́n ń fò kaakiri ojú ọ̀run. Ṣùgbọ́n ki ni kan ba aja o jẹ́, apá ẹranko náà gùn ju itan lọ, àwọn ọkùnrin mẹ́ta t;i wọ́n jẹ́ aṣáájúnínú àwọn ọmọ ọba yìí kò ní obìnrin. Ìdí rẹ̀ sì ni èyí pé, obìnrin kò lè ní ọkọp mẹ́ta pọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Bí ọ̀rọ̀ náà ti rí nì yìí: Ọkùnrin kan wà tí ó ti jẹ́ ọ̀rẹ́ ọba kí ọba tó gun orí oy’w. Kété tí ọba sì joyè tán ni ọkùnrin náà kú bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rẹ́ òun àti ọba pọ̀ gan-an ni. Ọkùnrin yìí bí ọmọbìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹwàdàpọ̀, àti ìgbà tí ó sì ti kú ni ọba ti fi ọmọbìnrin yìí ṣe ọmọ rẹ̀ tí ọmọ náà ń gbé ààfin. Ẹwadapọ dára ni ọmo, ẹ̀gàn ló kù. Gbogbo ara rẹ̀ ba ara wọn mu: orí kò tóbi ju ibi tí ó yẹ, ọrùn kò kéré kọjá ìwọ̀n, bẹ́ẹ̀ ni tapátẹsẹ̀ bá ara wọn jọ, ọmọ dára tán, \wà tún ṣubú lù ú, Ẹwadàpọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, ìwọ̀ntunwọ̀nsì lobìnrin. Aṣọ́ bá ara jọ, ìlẹ̀kẹ̀ ṣe ìwọ̀n ọrùn, ẹsẹ̀ bá bàtà ṣe dọ́gbadọ́gba. Ẹni tí Ẹwadàpọ̀ rẹ́rìn-ín sí, olúwarẹ̀ ṣe àríyá, ẹni tí o kí olúwarẹ̀ pa màlúù mẹ́tà, ẹni tí ó mọ́ lójú olúwarẹ̀ ṣubú lulẹ̀ ó tàkìtì méje. ẹni tí àwọn ọmọ ọba ń fẹ́ láti fẹ́ ni èyí. Ìgbà tí ọba gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó pinnu òun ó fi Ẹwadapọ fún èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ òun tí ó bá lè ṣe nǹkan tí ó jọ òun lójú jùlọ. O pe àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta, o fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ni àpò owó mẹ́ta, o ní kí wọ́n kúrò ní ìlú kí wọ́n lọ lo owó tí òun ffún wọn fi ra nǹkan tí ó bá jẹ́ ìyanu wá àti pe ẹni tí nǹkan tiẹ̀ bá ya ni lẹ́nu jù ni yóò fẹ́ Ẹwadapọ, ìwọ̀ntunwọ̀nsì lobìnrin. Àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta jùmọ̀ kúrò ní ilé, an rìn títí wọ́n fi dé oríta mẹ́ta kan báyìí. Ibẹ̀ ni wọ́n sì ti pínyà, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àdéhùn pé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́ dé oríta yìi’nígbà tí ó bá ń padà bọ̀ níláti dúró síbẹ̀ de àwọn méjì tí ó kù. Èyí àkọ́bí lọ, o rí ẹni kan rà. Bí ènìyàn bá jókòó lé e, ibikíbi tí ó bá wí pé kí ẹní yìí gbé òun lọ, wéré ni yóò bá ara rẹ̀ níbẹ̀ kò ní ló ju ìṣẹ́jú kan. Èyí àtẹ̀lé rí ìwo àgbáǹréré kan rà, tí ó lu ihò láti apá kan dé apá kejì bí ènìyàn bá gbé ojú bọ ọkan nínú àwọn ihò yìí, ibikíbi tí o bá wí pé òun fẹ́ lati rí ní òde ayé yìí ni yóò rí kedere. Èyí àbíkẹ́yìn rí èso igi kan rà, èso igi yìí kìí bàjẹ́, ó le koko ṣùgbọ́n kò sí àìsàn kan ní ayé yìí tí eso igi náà kò le wò, bí aláìsàn bá ti gbóòórùn rẹ ṣá, kí aláìsàn dìde ni. Ìgbà tí ó ṣe, àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta padà dé oríta. Ìgbà tí wọ́n sì ròyìn ohun tí àwọn rí rà fún ara wọn tí ẹni tí ó ra ìwo agbáǹréré sọ nǹkan tí ó wà fún, wọ́n ní ó yẹ kí àwọn fi ìwo náà wo Ẹwadapọ̀ nítoríu ẹni tí àwọn tilẹ̀ ń ṣá kiri ṣùgbọ́n kí ni wọ́n máa rí? wọ́n rí í pé inú àìsàn ní Ẹwadapọ̀ wà, àìsàn náà le, bí ó bá sì tó ìṣẹ́jú mẹ́wàá si i, dandan ni kí ọmọ náà kú. Wéré wọ́n lọ sí iyààrá Ẹwadapọ. Bí wọn sì ti dé ọ̀hún, wọ́n mu èso igi ìwòsàn, wọ́n fi si i ní imú, gbígbóòórùn tí Ẹwadapọ̀ gbóòórùn rẹ̀ báyìí, ṣe ló dìde gáú, ara rẹ̀ ti le. Ìgbà tí ọba gbọ́ bí gbogbo rẹ ti rí, ó pè àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ́ẹ̀ta, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ó ní: Ẹ̀yin ọmọ mi, mo ní ayọ̀ láti sọ fún yín pé, gbogbo yin ni ẹ ẹ dáadáa nínú ìdánwò tí mo gbé kalẹ̀ níwájú yín, kò sí ẹni tí mo lè fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn pé kò rí ohun ìyanu mú bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni bí gbogbo yín kò bá pa ara pọ̀ lo ohun iyanu yín, Ẹwadapọ̀ kò bá tí wà láyé lónìí. Nítorí bí kò bá sí ìwo àgbáǹréré àràmàǹdà, ẹ kò bá tí mọ̀ pé ara olùfẹ́ yín kò le, bí kò bá sí ẹní ìyanu, ẹ kò bá ti lè de ilé tí òun ìbá fi kú, bẹ́ẹ̀ ni bí kò bá sí èso igi ìgbàlà ẹ kò bá ti lè yọ Ewadapọ̀ nínú àìsàn rẹ́. Nítorí èyí, kò sí ẹni tí ó yẹ ki ń fún ni Ẹwadapọ̀ nítorí ohun tí ẹ mú bọ̀, ìdánwò mìíràn ni mo máa ṣe fún yín, ẹni tí ó bá ṣe dáadáa jùlọ nínú èyí nì ní yóò fẹ́ Ẹwadapọ̀, ìwọ̀ntunwọ̀nsì lobìnrin. Ẹ lọ mú apó àti ọfà yín, kí ẹ jẹ́ kí a lọ sínú pápá ti ń bẹ lẹ́yìnkùnlé mi, ìgbà tí a bá dé ọ̀hún, kí olúkúlùkù ta ọ̀fà síwájú, ẹni tí ọfà rẹ̀ bá rìn jìnà jù ni yóò ṣe baálé Ẹwadapọ̀, ìwọ̀ntunwọ̀nsì lobìrin. Àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ́ẹ̀ta yìí gbọ́ ọ̀rọ̀ bàbá wọn, olúkúlùkù bá ilé rẹ̀ lọ, gbogbo wọn mú apó àti ọfà, ó di ẹ̀yìn kùnlé baba wọn. Èyí ẹ̀gbọ́n ni ó kọ́ ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì rìn gidigidi, ṣùgbọ́n nígbà tí è’yi àtẹ̀lé ta ọfà tirẹ̀, o lọ títí wọ́n wá a, wọn kò ri i. Ìgbà t;i àbíkẹ́yìn ta ọfà tiẹ̀, ọfà rẹ̀ ta ti ọ̀gbọ́n rẹ̀ ìṣáájú yọ, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ọba ṣe ìdájọ́ báyìí pé, níwọ̀n ìgbà tí a kò ti mọ ibi tí ọfa àtẹ̀lé dé, oun kò le ṣe ọkọ obinrin yìí, níwọ̀n ìgbà tí ọfa tí ẹ̀gbọ́n ta kò dé sì ti dé ibi tí àbíkẹ́yìn, òun náà kò le ṣe ọkọ Ẹwadapọ̀. Ṣùgbọ́n nítorí tí ọfà àbíkẹ́yìn kò rìn ní irin ìkọsẹ̀ rárá, dandan ni kí òun ṣe baálé Ẹwadapọ́, ìwọ̀ntunwọ̀nsì lobìnrin. Eléyìí mú kí ẹ̀gbọ́n àgbàlagbà wọ inú igbó. Nítorí bí ìfẹ́ obìnrrin bá wọ ọkùnrin tọ́kàn tán tí wọ́n kò sì rí àyè fẹ́ ara wọn, ìdàrúdàpọ̀ a gba ìsàlẹ̀ odò ikùn, ìbànújẹ́ a da orí àgbà kọ odò, òkèlè kò nì lọ ní ọ̀nà ọ̀fun, ìrora olúwwarẹ̀ a ju ti onísòbìyà, ìrònú á dé bá olúwarẹ̀ bí onígbèsè, ọkàn olúwarẹ̀ á bàjẹ́ bii ti ẹlẹ́wọ̀n, ìrìn ẹsẹ̀ olúwarẹ̀ a dàbí ti olókùnrùn, ètè olúwarẹ̀ a gbé bi ti aboyun, itọ́ ẹnu olúwarẹ̀ a yi tikẹ́ bí ti ẹni ti ń sáré ìje, ìsọ̀rọ̀ olúwarẹ̀ a dàbí ti ará oko, ojú olúwarẹ̀ á dàbí tí ẹlẹenga, ara olúwarẹ̀ á gbóná bí ara alákọ̀wé tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ pé òun re ẹ̀yìn nínú ìdánwò, olúwarẹ̀ a sì máa kọsẹ̀ nibi ti kò sí gbòngbò ttàbí òkúta. Nítorí ìdí èyí, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń tan àwọn obìnirn jẹ pé àwọn ó fẹ́ wọn láìjẹ́ pé o ti inú ọkàn wọn jáde, àti àwọn oníyèmejì ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n ń tan ogunlọ́gọ̀ ọkùnrin jẹ lójoojúmọ́ ayé wọn apànìyan ni gbogbo wọn, Olódùmarè ṣe ayé ní iyọ̀ òyìnbó fún àwọn ọmọ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀n-ọnnì ńn fẹ́ sọ ọ́ di ewúro. Èyí àtẹ̀lé nínú àwọn ọmọ ọba yìí tí kò mọ òpin ọfà ti òun, kò dákẹ́, ó rọra dìde ó ń wá ọfà rẹ kiri, ó rìn títí kò tètè rí i ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe, ó ri i, bí o sì ti ń fẹ́ mú u, ni ó rí ìlẹ̀kùn kékeré kan tí ó bá ihò ilẹ̀ lọ. Ìgbà tí o sí ìlẹ̀kùn yìí wò, ó rí àkàsọ̀ kan tí ó lọ sí gbọn-ọnran sí ìsàlẹ̀ ó bá ń tọ àkàsọ́ yìí lọ. Nígbà ti ó sọ̀kàlẹ̀ tán, ó bá ara nínú ààfin tí ó kún fun dúkìá gbogbo, bí o sì ti wo iwaju ó rí obìnrin arẹwà kan tí ó jókòó lé orí àga ńlá kan. Ìjókòó ọmọbìnrin yìí ju ti ọba kọba nínú ayé wa, ẹwà rẹ̀ pàápàá sì tayọ ti ọmọ ènìyàn, ara rẹ ń dán bí ara ọmọ tuntun òòjọ́, àti apá àti ẹsẹ rẹ̀ yó bọ́rọ́bọ́rọ́ bí ẹni pé kò sí egungun níbẹ̀, ọmọ ìka ọwọ rẹ̀ yoo dàbí ara kòkòrò orí ọ̀pẹ, àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ mọ́ tónítóní ó dàbí ọjẹ̀lẹ ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀, ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ̀ dàbí òòrùn ọ̀sán gangan ti ń tan ìmọ́lẹ̀ púpọ̀, iroyin ọmọbìnrin náà rékọjá ohun sísọ. Nígbà tí ó rí ọkùnrin yìí, ó rẹ́rìn-ín músẹ́, eyín ẹnu rẹ sì funfun tó bẹ́ẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ lè sọ ọmọkùunrin di wèrè, nígbà tí ó sì wo ọkùnrin náà lójú ó ṣe bí obìnrin àfẹ́sọ́nà ti n tíjú ọkọ rẹ̀ tuntun. O dáhùn ó ni, ‘Èmi ni ọmọ aládé ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ìkáwọ́ bàbá mi ni gbogbo wúrà, fàdákà, díámọ́ǹdì àti gbogbo òkúta olówó iyebíye inú ilẹ̀ ń bẹ. Ní ọdún kẹẹdọ́gbọ̀n tí wọ́n ti ṣe ìsẹ̀dálẹ̀ mi, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta iwin ni wọ́n wí pé àwọn ń fẹ́ fẹ́ mi, ṣùgbọ́n mo kọ̀ fún wọn; ní ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ni wọn tún n fẹ́ fẹ́ mi, ṣùgbọ́n mo tún kọ̀ fún wọn. Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ aládé àwọn ẹbọra ni mi, síbẹ̀, ọkàn wọn kò fà mí, n kò ní ìfẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n, ìwọ, ọmọ ènìyàn, ni ó wà lẹ́mìí mi. Ó pẹ́ tí mo ti mọ̀ ọ̀ láì jẹ́ pé ìwọ mọ̀ mí, ó pẹ́ tí mo ti ri ọ láì jẹ́ pé ìwọ mọ̀ pé mo rí ọ. Ìwo àgbáǹréré rẹ kò ṣẹ́yìn mi, ẹní àràmàńdà ẹ̀gbọ́n rẹ, mo mọ̀ nípa rẹ̀, èso igi ìmúláradá àbúrò rẹ kò jẹ́ ìpamọ́ fún mi, ìyà ìfẹ́ tí ìwọ jẹ́, kò ṣókùnkùn lójú mi, ṣùgbọ́n ìwọ ni iye lórí ju ohun tí ìwọ ń lépa, ìwọ sàn ju ẹni tí ìbá fẹ́ Ẹwàdapọ̀ lọ. Báyìí ni ọmọbìnrin yìí sọ, ìgbà tí ọkùnrin náà dá a lóhùn pé òuun kò yẹ ní ẹni tí ìbá gbọ́ irú ọ̀rọ̀ yìí lẹ́nu ọlọ́lá bẹ́ẹ̀ ọmọbìnrin náà tún dáhùn ó ni: ‘A! Ìwọ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ lo mú ọ sọ irú èyí. Ìwọ jù mi lọ, ìwọ tóbi nínú àwọn ọmọ ènìyàn, ìwọ pọ̀ lọ́kùnrin. Jọ̀wọ́ jókòó tì mí, máa bá mi ṣiré, nítorí mo wà ní èmi nìkan, alábàáṣiré sì ń wù mi.’ Wéré ọkùnrin yìí gbá, ó jókòó ti ọmọ aládé ìsàlẹ̀ ilẹ̀ kò sì sí nǹkan tí onítọ̀hún kò ṣe tan láti mú kí inú rẹ dùn. Bí iré bí iré wọ́n mọ ojú ara wọn, bí iré bí iré wọ́n ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀, bí iré bí iré wọ́n ń sọ̀rọ̀ ọkọ òun aya, láìfa ọ̀rọ̀ gùn lọ títí, wọ́n gbé ara wọn ni ìyàwó. Bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ náà, ti ìgbéyàwó da ara òde ọ̀run pọ̀ mọ́ ara ayé, ẹbọra ń gún iyán, ẹbọra ń ro ọkà, ẹbọra ń ṣe alága, ẹbọra ń ṣe olórí ẹgbẹ́, àwọn ará òkè àti ti ìsàlẹ̀ n jùmọ̀ ṣe àríyá pọ̀, nǹkan ṣe ní òde ọ̀run. Ọkùnrin yìí gbé pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ fún odidi oṣù mẹ́fà kí ó tó rántí ilé. Nígbà tí ọkàn bàbá rẹ̀ sì fà á, ó tọrọ ààyè lọ́dọ̀ ìyàwó rẹ̀ láti lọ̀ bẹ ilé wò, òun náà sì gbà pé ó dára, ṣùgbọ́n ofin kan ni o fún ọkọ rẹ̀, ó wí fún un pé kò gbọdọ̀ sọ ibi tí òun wà fún ẹnikẹni, ṣùgbọ́n kí ó fi han bàbá rẹ̀ pé ọkàn òun balẹ̀ nibi tí òun wà, àti pé ayé òun ti dára. Ìgbà tí ọkùnrin náà máa jáde nínú ààfin ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ó jáde bí ọba. Àwọn ẹlẹ́sin tí wọ́n jọ́ arẹwà ti wọ́n ṣe ẹsin wọn ni ọ̀sọ́, àti àwọn wúndíá tí wọ́n to ara wọn sínú mọ́tò ayọ́kẹ́lẹ́ pẹ̀ú ogunlọ́gọ̀ àwọn ẹ̀dá tí wọ́n wà lórí alupùpù tuntun, ni wọ́n to ara wọn jọ síwájú ọkùnrin náà bí òun ti ń bọ̀ nínú mọ́tò ayọ́kẹ́lẹ́ gbọ̀lọ̀kù kan bí àtàtà ọba. Nígbà tí ọkùnrin yìí yọ sí ìlú bàbá rẹ̀, ariwo ta, nígbà tí ó sì dé iwájú bàbá rẹ̀ tí ó dọ̀bálẹ̀, tí bàbá rẹ̀ náà sì mọ̀ pé òun ni, ó yọ̀ bí ẹni pé ọjọ náà ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fi jọba. Bàbá yìí ṣe ìtọ́jú ọmọ rẹ̀ púpọ̀, bàbá àti ìyá a maa pa àṣíírí ọmọ wọn mọ́, ìgbà tí bàbá sì ti béèrè ibi ti ọmọ náà wà tí onítọ̀hún sì ti wí pé òun kò le sọ àti pé àlàáffíà ni òun wà ni bàbá náà kò ti ṣe aápọn àti wádìí eléyìí mọ́, nítorí rírí tí ó tilẹ̀ rí ọmọ rẹ ti ta ohun gbogbo yọ. Ọkùnrin yìí bá bàbá rẹ ṣíré títí ilẹ̀ ọjọ́ náà fi ṣu, ìgbà ti ilẹ̀ ọjọ́ kejì sì mọ́ ó padà lọ sí ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Àti ọjọ́ yìí ni ọmọ náà ti máa ń wa kí bàbá rẹ̀ ti o n ṣe bí ọba tí inú bàbá rẹ̀ sì ń dùn, ṣùgbọ́n ibi ti o tì ń wá ṣókùnkùn lójú ẹnikẹ́ni. Nígbà tí o ṣe, ọmọ araye bọ́ sí aarin ọmọ àti bàbá yìí, ọkùnrin kúkúrú bìlísì kan lọ sí ọdọ bàbá ó sọ̀rọ̀ báyìí fún un o ni: Kábíyèsí, kí ọlọ́run bùn yín lẹ́mìí, é ó pẹ́ láyé fún wa. Apá ọ̀tá ko ní ka yín, ọmọ aráyé kò ní lè fi yín ṣe nǹkan, àwọn ẹyẹ kìí ṣàìri ounjẹ òòjọ́ jẹ, ẹ kò ní ṣàì rí oúnjẹ jẹ laelae, ẹjá kìí tan nínú omi, ọmọ kò ní tan nínú ilé yín láéláé. Kábíyèsí, ayé ṣòro, ẹ̀yin àgbàlagbà sì ti wí pé ilé ni a ti ń ko ẹ̀sọ́ ròde, ilé ni ikú wa, orúkọ ẹran àjàyí, ayanmopin ẹran olugbode, ará òde kò mọ ni gẹgẹ bí ẹrú, ara ilé níí tọ́ka sí ni. Ọmọ yín yìí, ọmọ ńlá ni. Láìsí àní àní, ọmọ náà gbójú lé nǹkan. Àwọn ọmọ ìwòyì kò dára o, ẹ má ṣe fi ara sílẹ̀, nítorí bí mo ti ń wòye yìí, bí ẹ kò bá sọ̀ra, ọjọ́ ń bọ̀ tí ọmọ náà yóò kó àwọn ọmọ ogun wá, ti wọn yóò ba a yín jà, ti wọn yóò le e yín kúrrò lórí ìtẹ́. Kí Ọlọ́run bùn yín lẹ́mìí Kábíyèsí. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, òjò òwúrọ̀ ni ń bí olówó nínú, olówó a gẹlẹtẹ, ìwọ̀fà a sì gẹlẹtẹ, irú ọ̀rọ̀ yìí kò le ṣàì fa ìbànújẹ́ wa, inú sì bẹ̀rẹ̀ sí bí bàbá yìí bí ó bá ti rí ọmọ rẹ̀. Èrò rẹ̀ ti yípadà, nítorí bí ó ti wù kí bàbá fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ tó, kò sí ẹni tí o lè fẹ́ kí ọmọ òun pa òun. Bàbá yìí bẹ̀rẹ̀ síí wá ọ̀nà àti mú ọmọ rẹ̀. Ó pe ọmọ rẹ̀, ó wí fún un kí o lọ̀ bá òun wá nǹkan tí ó ṣòro. Ó wa àwọn ènìyàn burúkú ti wọ́n wádìí tí wọ́n sì ti mọ ibi tí ọmọ rẹ̀ ń gbé. Àsẹ̀yìnwá Àsẹ̀yìnbọ̀ o jẹ́wọ́ fún ọmọ rẹ̀ pé òun ti wádìí òun sì ti mọ ìdí rẹ̀, òun ti mọ ẹbọra tí o jókòó tì, ó sì rán an kí ó lọ bèèrè lọ́wọ́ ẹbọra ìyàwó rẹ̀, kí óo bá òun wá aṣọ títóbi kan tí ó jẹ́ pé bí ènìyàn bá ká aṣọ yìí tán tí dìí mọ àtẹ́lẹwọ́ kan ẹnikẹ́ni kò ní í rí ohun tí olúwarẹ̀ dì mọ́ ọwọ́, ṣùgbọ́n bí ènìyàn bá nà án tán, yóò bo gbogbo ìlú. Pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni ọmọ náà fi kúrò lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀ tí ó lọ sí ààfin isalẹ ilẹ̀, nítorí nní ọjọ́ tí ẹnikẹta bá ti bọ́ sí ààrin olùfẹ́ méjì, ayọ̀ a ki iré mọ́lẹ̀ a sáré bí ẹranko tí ó gbúròó ajá ọdẹ, ìbànújẹ́ a gbé àga Òy��nbó, á fẹ̀yìntì dípò ayọ̀, ayé a yí, nǹkan a di rúdurúdu. Nígbà tí ọkùnrin yìí yọ sí ìyàwó rẹ̀, ó fa ojú ro, ṣùgbọ́n nígbà tí onítọ̀hún bèèrè ìdí ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún un, ṣe ni ìyàwó rẹ̀ bú sí ẹ̀rín, tí ó wí pé èyí ni kò tó nǹkan, ó dáhùn ó ní, ‘Aṣọ tí bàbá rẹ bèèrè wà ní ìsàlẹ̀ àpótí mi, àwọn èenìyàn ti bọ́ sí ààrin rẹ àti bàbá rẹ, ṣùgbọ́n eléyìí nì kò tó nǹkan ohunkóhun tí ó bá dé sí ọdé sí mi ti àwọn onítọ̀hún ló ṣoro.’ Ní ọjọ́ kejì ni ọkùnrin yìí mu aṣọ náà lọ. Ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ tán wí fún un pé kí ó lọ bá òun wá ewé igi kan ti ń bẹ ní orísun omi òkun. Bí ènìyàn bá já ewé igi yìí kìí bàjẹ́ láéláé, yóò máa dúdú ni, ojoojumọ ti olúwarẹ̀ bá sì tí lọ sí ibi tí ó fi ewé náà sí, owó góòlò ńlá kan ni yóò máa bá lábẹ́ rẹ̀. Pẹ̀lú ìbínú ni ọmọ yìí fi jáde níwájú bàbá rẹ̀. Ìgbà tí o sì dé ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀, ìyàwó bu omi sùúrù fún un mu ó wí fún un kí ó máṣe bínú níwájú bàbá rẹ̀ mọ́. Kí Ọlọ́run fún ni ní ìyàwó àlàáfíà. Wéréwéré ló bá a wá ewé igi ti bàbá rẹ̀ béèrè yìí. Nígbà tí ọkùnrin náà tún mu ewé yìí dé ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ kò dákẹ́ ó tín bèèrè ohun mìíràn, o ní, ‘mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, ọmọ mi. Kí ní kan péré ló wá kù tí mo fẹ kí o ṣe fún mi. Mo fẹ́ kí o lọ pe iwin kan kí ó wá fi ojú kàn mi, mo ti ń gbúròó iwin náà ti pẹ, kò ga ju ẹsẹ̀ bàtà méjì lọ, irungbọ̀n rẹ̀ gùn tó ọgbọ̀n ẹsẹ̀, o sì gbe irin kan lé èjìká tí ó wúwo tó àpò èkùrọ́ mẹ́jọ tí ó kún dé ẹnu. Yára tètè lọ kí o pè é kí o wá rí mi, ọọku o, ọmọ mi. Ọkùnrin yìí rọra díde kò fọhùn, nítorí ọ̀rọ̀ ti pa èsì jẹ. Ó bẹrẹ sí í pòṣé títí ó fi dé ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀. Nígbà tí ìyàwó yìí sì gbọ́ ìbéèrè náà ó bú sẹ́rìn-ín ó ni, ‘A! Ẹ̀gbọ́n mi ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Ìwà ìṣẹ̀dá ẹ̀gbọ́n náà yàtọ̀ ṣá, bí bàbá rẹ kò bá sọ́ra yóò pa a, nítorí ọ̀gbọ́n mi náà ba nì lẹ́rù lọ́pọ̀lọpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í fẹ́ kí ẹnikẹ́ni bẹ̀rù òun, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀ a na irin mọ ọ lórí, á pa á dànù wéréwéré.’ Lọ́gán, obinrin yìí kígbe ǹlá pe ọ̀gbọ́n rẹ̀ náà láti ọ̀nà jíjìn réré, pnítọ̀hún náà sì dáhùn bí ìgbà tí jàgídíjàgan obìnrin bá da orogún rẹ̀ ní ohùn líle. Ìgbà tí iwin náà ń bọ̀ gbogbo ìsàlẹ̀ ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sii lù kìkì bí ẹwìrì àggbẹ̀dẹ, gbogbo agbegbe ń pariwo bí ìgbà tí omi ńlá bá ń sọ̀kalẹ̀ lórí àpáta, ogunlọ́gọ̀ àwọn iwin ti wọn ti ń ṣe ìránṣẹ́ fún tọkọtaya yìí ni wọ́n dákẹ́ pátápátá tí wọ́n sá lọ bámúbámú, ẹ̀rù ba ènìyàn, ẹ̀rù ba ẹbọra. Nígbà tí ó yọ, , àbúrò rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síi kíi, ẹ máa wolẹ̀, ẹ máa rọra, ẹ máa wọlẹ̀, ẹ máa rọra, a bu ọla fún yín, a ba búrúbúrú, ẹ máa wolẹ̀ ẹ̀gbọ́n mi, ẹ máa rọra, ẹ máa rọra, ọmọ onílẹ̀ tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́, àjèjì tẹ̀ ẹ́ gìrìgìrì, ẹ̀yin lẹ ni mi, ẹ̀yin lẹ ni lẹ̀.’ Báyìí ni obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ si i kí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí ojú rẹ̀ pupa bí òòrùn alẹ́, ìgbà tí o sì ti béèrè ìdí rẹ̀ ti àbúrò fi pè è tí àbúrò rẹ̀ ti sọ fún un, ni o ti wí fún ọkùnrin náà kí ó bọ́ síwájú tí òun náà tẹw lé e, pẹ̀lú irungbọ̀n rẹ̀ ti ń wọ́ ilẹ̀ gurugurum, wọ́n múra, ó di ọ̀dọ̀ ọba ti o ń fẹ́ ri i. Bí iwin àti ènìyàn yìí ti ń bọ̀ ni gbogbo ẹni ti o rí wọn ń bẹ́ lu igbó, ìgbà tí wọ́n sì dé ààrin ìlú, wọ́n kọ orí sí ààfin. Bí wọ́n ti wọ ibi tí ọba yìí jókòó sí, wọ́n bá àwọn ìjòyè rẹ̀, ọba sì bẹ̀rẹ̀ síó gbọ̀n bí ẹni tí òtútù ń pa, gbogbo ẹ̀wù rẹ̀ ń fẹ́ lẹ́lẹ́ bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù ń fẹ́ igi oko. Ìgbà tí iwin yìí sọ̀rọ̀ síi kò le dáhùn, inú bí iwin nítorí èyí, ó na irin mọ́ ọ lórí, orí fọ, ìmùdùnmúdùn hàn gbangba, ikú dé. Iwin tún wo àwọn ìjòyè, ó dá sèríà fún gbogbo wọn, ó pa wọ̀n, ó pe gbogbo ìlú jọ, bí wọ́n fẹ́ bí wọ́n kọ̀, wọ́n dé, o tún múra ó fi ọkùnrin tí ó jẹ́ ọkọ àbúrò rẹ̀ jọba, o lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ó pe àbúrò rẹ̀, wéré eléyìí nì di ayaba. Báyìí ni ìtàn náà párí – eléyìí ni ìtàn kẹta tí a gbọ́ nínú ilé Òpìtánparapọ̀. Nígbà tí a wòye pé ilẹ̀ ń ṣu lọ èmi àti ìyàwó mi díde, a múra ó di ibi tí à ń gbé, ọjọ́ kejì ni a sì kúrò ní ìlú yìí. ÌLÚ ÌTÀNJẸ-ÈNÌYÀǸ Ọ̀ pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni a fi ojú rí nígbà tí a kúrò ní ìlú yìí tán ṣùgbọ́n kò sí ààyè nísisí yìí láti sọ gbogbo wọn. Síbẹ̀síbẹ̀ náà, n kò gbọdọ ṣáì sọ nǹkan tí ó sẹlẹ̀ sí mi ní ìlú tí à ń pè ní Ìtànjẹ-ènìyàn. Kò sí ẹni tí ó wà ní òde ayé yìí tí kò ní àgbélèbú tirẹ̀. Àgbélèbú kìí sii tilẹ̀ fi ibì kan rere sílẹ̀ ni igbá kejì mi, Ayédèrúẹ̀dá. Mo rò pé ẹ o ranti irú ọ̀rọ̀ burúkú tí ó sọ níwájú Òmùgọ́diméjì ọba ìlú àwọnn Èdìdàrẹ́ ẹ ó sàkíyèsí pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ju àti fi wa ojú Òmùgọ́diméjì mọ́ra lọ. Ayédèrú-ẹ̀dá jẹ́ ẹnikan tí a lè wí pé ó ti kọ́ ilé fún rìkíṣí ni agbárí, tí ó ti fún àgàbàgebè ní iyààrá, tí òun àti wọ̀bíà jọ ń fi ọwọ́ kọ́ ọwọ́ rìn kiri. Ó mọ ọ̀nà rìkíṣí lọ́pọ̀pọpọ̀, o sì mọ̀ ọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé bí o ń pa ènìyàn lọ báyìí olúwarẹ̀ yóò máa wí pé kò sí ọ̀rẹ́ òun tí ó to o. Ní ìgbà ìyàwó mi, òun àti àbúrò ìyàwó mi ti bbẹ̀rẹ̀ si i ṣe ọ̀rẹ́ pẹ̀lú ara wọn, ọ̀rẹ́ wọn yìí kò kúkú hàn sí wa jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n wọ́n ti ń pàdé ara wọn ni ìkọ̀kọ̀ lẹ́ẹ́kọ̀ọ̀kan kí ó tó di nǹkan bí osù méjì lẹ́yìn tí mo gbéyàwó. Àbúrò ìyàwó mi yìí bá wa kúrò ní odò Ìrántí, nítorí ó fẹ́ràn ìyàwó mi púpọ̀. Eléyìí mú kí òun àti Ayédèrú-ẹ̀dà máa rí àyé bá ìfẹ́ ara wọn lọ. Kò pé nígbà tí ìgbéyàwó mi parí tí a rí ọwọ́ òsì Ayédèrú-ẹ̀dá tí ó rọ, ọwọ́ ọ̀tún lo fi ń gbé ìbọn láti ìgbà náà lọ a kò sì mọ ìdí, rẹ̀ tí ọwọ́ náà fi rọ. Nígbà tí a dé ìlú Itanjẹ-ènìyàn yìí, ayédèrú-ẹ̀dá pè mi sí [[ikọ̀kọ̀ lọ́jọ́ kan, ó wí fún mi pé ki ń máṣe gbẹ́kẹ̀lé ìyàwó mi, nítorí alaalẹ́ ni ìyàwó mi àti ọkùnrin kan ń pàdé ara wọn tí wọn sì ń fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu tí wọ́n ń lọ́ mọ ara wọn gídí gbágbá. Ó wí fún mi pẹ̀lú pé bí n kò bá gbàgbọ́ òun ṣet;an láti lọ mu mi rí ìyàwọ mi nibi tí òun àti ọkùnrin ọlọ́kùnrin ti ń lo ìfẹ́ pẹ̀lú ara wọn. Eléyìí yà mi lẹ́nu lọ́pọ̀lọpọ̀, mo sì wí fún un pé kí o jọ̀wọ́ má ṣàì mú mi lọ. Àṣé Ayédèrú-ẹ̀dá ti wí fún àbúrò ìyàwó mi pé kí ó ró aṣọ ìyàwó mi, kí o wwé gèlè rẹ̀, kí o sì mú ìbòrùn rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tí à ń wí yìí kí o wá pàdé òun, nítorí òun tilẹ̀ fẹ́ wò bí olùfẹ́ òun ti dára tó nínú aṣọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀! Ìgbà tí ilẹ̀ ṣu, tí ayédèrú-ẹ̀d[‘a sọ fún mi pé kí a jọ lọ, ó mú dé ibi kan báyìí, o fi mi síbẹ̀, o ní òun ń padà lọ sí ibi tí òun ń gbé ní ìlú náà, ki ń máa wòran, n o fi ojú mi rí ìyàwó mi àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọkùnrin. Ó bá lọ. Àṣé bí ó ti lọ tán, ṣe lo lọ yí aṣọ padà. Ìgbà tí ó sì ṣe ni mo rí àbúrò ìyàwó mi ti o ń bọ̀ nínú aṣọ ìyàwó mi. Mo ṣe bi ìyàwó mi ni. Ìgbà tí ó sì dé ibi kọ̀rọ̀ kan báyìí tí ó dúró, ṣe ni mo rí Ayédèrú-ẹ̀dá tí í dé, ó ti yí aṣọ padà, kò sì jọ oun mọ́ rárá, ni òun àti àbúrò ìyàwó mi bá bẹ̀rẹ̀ síí lọ́ mọ́ ara wọn wọn n fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu. Ara mi gbóná já gbàà, mo múra mo lọ sí ilé mo lọ pọ́n àdá mi sílẹ̀ pé ìgbà tí ó bá dé n o pa á ni. Nǹkan náà sì wá ṣe é tó bẹ́ẹ̀, ìgbà tí mo dé ilé, ìyàwó mi lọ sí òde. Ó pẹ́ kí ó tó ti òde náà dé, mo jókòó lórí àga kan ìgbà tí mo jókòó títí tí kò dé, mo sùn lọ. Ìgbà tí mo tají ààrin ọ̀gànjọ́ ni, ìyàwó mi ti wọ ìyààrá rẹ̀, ó sí ìlẹ̀kùn sílẹ̀. Èmi náà mú àdá, ó di ọ̀nà ìyààrá rẹ̀. Bí mo ti n lọ ti mo fẹ́ wọlé, se ni mo rí ti ògiri ẹnu ọ̀nà ní apá ọ̀tún àti apá òsì súnmọ̀ ara wọn, tí wọ́n pade sinsin tí kò sì sí ojú ọ̀nà mọ́, mo bá padà, mo lọ dúró. Bí mo ti dé ibi ti mo kọ́ dúró mo tún rí i pé ògiri yìí bìlà sẹ́yìn, ìlẹ̀kùn ìyààrá ìyàwó mi tú sí, mo múra ó di ibẹ̀ pẹ̀lú àdá mi. Ṣùgbọ́n bí mo tún ti fẹ́ wọlé ogiri padà, n kò rí ojú ọ̀nà mọ́, mo tún lọ. Ìgbà tí ó di ẹ̀ẹ̀kẹta tí ogiri bílà sẹ́yìn tí mo rí ojú ọ̀nà tí mo lọ pẹ̀lú àdá mi, mo gbé ẹsẹ̀mi kan, ó rọra fún díẹ̀, kò fún un pupọ̀, ṣùgbọ́n n kò lè fa ẹsẹ náà yọ mọ́. Ìyàwó mi ti fi hàn mi pée iwin ni òun. Ẹsẹ mi ti bọ́ sí pàkúté, ń kò lè fà á yọ, n kò sí le ké nítorí ojú ń ti mi. Ibi yìí ni mo wà títí ilẹ̀ fi mọ́. Ìgbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìyàwó mi kò ba ibi ojú ọ̀nà ibẹ̀ jáde, ibòmíràn ló bá jáde, ko sì tilẹ̀ rìn wá apá ibi tí mo wà rárá, ó lọ, o ń wá oùnjẹ. Ìgbá tí ó wá oúhnjẹ tán, ó ké sí mi, bí o sì ti Ké bẹ́ẹ̀ ṣe ni mo rí ti ogiri bìlà sẹ́yìn tí mo fa ẹsẹ̀ mi yọ. Mo múra, mo ń lọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí mo ti yọ sii, ti mo ní ki n gbé àdá sókè, àdá wúwo o ju àkúta lọ, n kò sí lè gbé ọwọ́ sókè rárá. Ìyàwó mi bú sẹ́rìn-ín, ó na ọwọ́ o ní ki n mú àdá náà fún òun, mo mú u fún un. Lẹ́yìn èyí, o ní ki ń jẹun, mo ni kò jẹ, o fi dandan lé e, ìgbà ttí ó pẹ́ sá, mo bu òkèlè díẹ̀. Lẹ́yìn èyí ni mo ri i, tí ó dìde tí ó pa ilẹ̀ mọ́ tí ó di gbogbo ẹrù rẹ̀. Ìgbà tí o dì í tán, ó pè mi, lẹ́yìn náà ó pe àbúrò rẹ̀, ó bi i léèrè lójú mi ibi tí onítọ̀hún lọ ní alẹ́ ìgbà tí èmi ṣebi mo rí òun, onítọ̀hún sí ssọ ibẹ̀ fún un lójú mi. Ó béèrè aṣọ gbogbo tí o mu lọ, onítọ̀hún dáhùn, o ní aṣọ ìyàwó mi ni. Ó béèrè bí ẹnìkan wá bá a lẹ́hùn-ún, ó dáhùn, o ní ọ̀rẹ́ òun ọkùnrin wá báa òun, kò dárúkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà. Lẹ́yìn èyí, ìyàwó mi kọjú sí mi ó ni, ‘ṣe o gbọ́ bí ó ti sọ? Gbogbo nǹkan tí o rí lánà-án wà lọ́wọ́ mi, ẹni tí o rò pé èmi ni kìí ṣe èmi o.’ Ìgbà tí o wí báyìí tan, ó kọjù sí ẹru rẹ̀ tí o dì sílẹ̀, ó ni, Ẹ máa kó èyí lọ sílé mo ń bọ̀.’ Bí ó ti wí báyìí ni n kò rí ẹrù náà mọ́ bẹ́ẹ̀ ni n kò rí ẹni tí o sọ̀rọ̀ sí. Lẹ́yìn èyí ó kọjú sí mi ó ni, Háà! Ìrìnkèrindò, bí mo ti ṣe tó, síbẹ̀ o kò gbẹ́kẹ̀lé mi! Èmi! Èmi náà! Ìrìnkèrindò, o tún di ẹni ti ń fẹ́ pa mi! Kí o pa mi, ki ń kú, Ìrìnkèrindò! O gbàgbé gbogbo bí mo ti jẹ́ fún ọ, bí mo ti máa ń kẹ́ ọ, tí mo máa ń gẹ̀ ọ, ti mo máa ń sá sókè sódò nítorí rẹ, gbogbo ìtọ́jú rẹ, ti mo ṣe nígbà ìyàwó o kò rántí mọ́, ìnáwó àwọn òbí mi, kò já mọ nǹkan kan fún ọ! Ha! Ìrìnkerindò! Ha! Ìrìnkèrindò! Mo dúpẹ́ o, mo dúpẹ́ o, mo dúpẹ̀ o, o ṣe é o, o ṣe é púpọ̀, mò ń lọ, o dìgbà, o dìgbà, o dìgbà abbl. Bí ìyàwó mi ti ń wí pé ‘o dìgbà’ ni ẹsẹ̀ rẹ̀ n wọ ilẹ̀ lọ; ddíẹ̀ díẹ̀ lo ń wọ ilẹ̀ lọ, ara mi gbọ́n, mo sì bẹ̀rẹ̀ sii bẹ̀ ẹ́ kí ó jọ̀wọ́ dáríjì mí, ṣùgbọ́n kò gbọ́, ọ̀ràn náà ti dùn ún jù. Nígbà tí mo rí Ayédèrú-ẹ̀dá ti mo bẹ̀rẹ̀ ìjà, o ní òun kò mọ̀ pé àbúrò ìyàwó mi ló wọ aṣọ ìyàwó mi, ibi ti òun jókòó sí lọ́jọ́ tí òun ti kọ́ ri wọn ni òun ní ki n jókòó sí, òun kò sì rò pé o yẹ́ kí òun rí ẹni ti òun rò pé ìyàwó mi ni kí ẹlòmìi’ràn máa lò ó bí òun ti rí wọn láì jẹ́ pé òun sọ fún mi, òun kò mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni àbúrò ìyàwó mi ṣe máa ń lọ pàdé ọkùnrín ọlọ́kùnrin kiri. Ìgbà ti o sì jẹ́ pé àti ìyàwó mi àti àbúrò rẹ̀ ko sí ẹni ti ó dárukọ Ayédèrú-ẹ̀dá nígbà tí wọn ń sọ̀rọ̀, n kò lè sọ pàtó pé irọ́ ni ayédèrù-ẹ̀dá pa. Ṣùgbọ́n nnkan tí o tún sẹlẹ lẹ́yìn èyí mú kí emi àti oun da ẹ̀yìn kọ ẹ̀yìn gan-an. Mo deedee ń lọ ni ẹni náà yìnbọn sí ojú ọ̀nà tí à ń bá lọ, díẹ̀ báyìí lo kù kí ìbọn náà bà mi, o sì dá ẹnikẹ́ni lójú pé ẹni tí ó yìnbọn náà fẹ́ pa ọ̀kan nínú wa ni, mo tilẹ̀ ṣebí àwọn ọ̀tá kan ni wọ́n ba sínú igbó tí wọ́n ń fẹ́ bá ni jagun ni, mo bá da ojú ìbọn kọ ibi tí ìbọn tí dún, ìgbà tí a sì lọ wo ibi tí mo yìnbọn sí, Ojúayédùn, ènìyàn ayédèrú-ẹ̀dá ni a bá, tí ìbọn ti bà tí ó ti kú pátápátá. Wéré ni Ayédèrú-ẹ̀dá kígbe pe gbogbo àwọn ènìyàn wa ti ń lọ kí wọ́n dúró, mo ti yìnbọn pa ènìyàn. Àwọn ọdẹ ṣe ìpàdé lé orí ọ̀ràn náà, ìgbà tí ó sì jẹ́ pé Ayédèrú-ẹ̀dá ni igbákejì mi, òun ni wọ́n yàn kí ó ṣe alága. Ìgbà tí o sì máa dá ẹjọ́, o ni nǹkan tí òun rò pé ó yẹ kí wọ́n ṣe ni pé kí wọ́n yìnbọn lu èmi náà. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ ọdẹ kò gbà. Wọ́n ni ikú tí o yẹ ki ó pa Ojúayédùn ni ó pa a, Ojúayédùn tí ó jẹ́ pé òun lo le kí ènìyàn ju ẹnìkan lọ, tí ó ń dọ̀bálẹ̀ fún àti ọmọdé àti àgbà nínú àwọn tí kò sì sí nǹkan ti kì�� fẹ́ ṣe láti fi wa ojú ènìyàn mọ́ra ko yẹ kí o hu irú ìwà tí o hù, ikú tí o yẹ Ojúayédùn ni Ojúayédùn kú. Gbogbo àwọn ọdẹ sì sọ̀ lójú gbangba báyìí pé èmi nikan ni àwọn lè gbẹ́kẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn. Báyìí ni mo yọ nínú ẹjọ́ náà, kò sì pẹ lẹ́yìn èyí tí a dé odó ẹjẹ̀. A ti kọja odó náà lẹ́ẹ̀kan, ni kété tí a kúrò ní ìlú àwọn Èdàdàrẹ̀ tí ó jẹ́ pé ọkọ̀ kékeré kan ni wọ́n fi tu gbogbo wa gòkè, ṣùgbọ́n ti ẹ̀ẹ̀kejì yìí, àfi bí ẹni pé kìí ṣe odò náà ni mọ́. Bí a ti ń súnmọ́ o ni a rí ti gbogbo igbó púpa yòò, tyi ibi gbogbo lápá ọ̀tún àti lápá òsì pa lọ́lọ́, àti ewé àti ẹeka igi àti ìtànná àti eso wọn gbogbo ló pupa ko sí ẹ̀dá alààyè kan ṣoṣo, ẹyẹ kò ké, ọ̀kẹ́rẹ́ kò gun igi, labalábá kò tilẹ̀ fò kọjá, bẹ́ẹ̀ a kò gbúròó esinsin. Nígbà tí o ṣe, a ri ẹnu ọ̀nà kan báyìí níwájú wa, wọn ri òpó irrin lápá ọ̀tún àti lápá òsì, wọ́n sí ṣe ìlẹ̀kùn sii, lóri òpó irin méjì yìí lókè ni wọ́n gbe igi gbi gbòòrò tí ó rí pẹlẹbẹ báyìí kà, lára igi yìí ni wọ́n sì kọ àkọlé yìí sí: JỌ̀WỌ́ JẸ́WỌ́ Ẹ̀SẸ̀ RẸ KÍ O TÓ KỌJÁ ODÒ Ẹ̀JẸ̀, ẸNI TÍ KÒ JẸ́WỌ́ Ẹ̀SẸ̀ RẸ̀ KÍ Ó TÓ KỌJÁ ODÒ Ẹ̀JẸ̀ A KÀN JÀǸBÁ, JỌ̀WỌ́ JẸ́WỌ́ Ẹ̀SẸ̀ RẸ KÍ O TÓ KỌJÁ ODÒ Ẹ̀JẸ̀. BÍ O BÁ JALÈ RÍ, JỌ̀WỌ́ JẸ́WỌ́ Ẹ̀ṢẸ̀; BÍ O BÁ PÀNÌYÀN JỌ̀WỌ́ JẸ́WỌ́ Ẹ̀ṢẸ̀; BÍ O SOJÚKÒKÒRÒ, JỌ̀WỌ́ JẸ́WỌ́ Ẹ̀ṢẸ̀; BÍ O FẸ́ OBÌNRIN OLÓBÌNRIN, JỌ̀WỌ́ JẸ́WỌ́ Ẹ̀ṢẸ̀, ẸNI TÍ KÒ JẸ́WỌ́ Ẹ̀SẸ̀ RẸ̀ KÍ Ó TÓ KỌJÁ ODÒ Ẹ̀JẸ̀ Á KÀNJÀNGBỌ̀N, JỌ̀WỌ́ JẸ́WỌ́ Ẹ̀ṢẸ̀ RẸ KÍ O TÓ KỌjÁ ODÒ Ẹ̀JẸ̀. Bí a ti dé ibi ìlẹ̀kùn yìí ni ìlẹ̀kùn sí fúnrarẹ̀ tí gbogbo wa sì wọlé. Ìgbà tí gbogbo wa wọlé tán, ìlẹ̀kùn padé, bí a sì ti wo ẹ̀yìn ni a rí ẹnìkan tí o gbé àáké ssókè tí o n tẹ̀lé wa. Ìgbà tí o kù díẹ̀ gan-an kí a dé odò ẹ̀jẹ̀ tí à ń wo irin tẹ́ẹ́rẹ́ kan ṣoṣo tí ó dúró bí afá sí orí odó náà ni a tún rí ẹnìkan níwájú tí ó gbé àáké lọ́wọ́ ti o ń dúró de ni. O wá jẹ́ pé níwá lẹ́yín ni a rí àwọn tí wọ́n gbé àáké yìí. Ìgbà tí a dé ọ̀dọ̀ èyí iwájú, tí o rí èmi ti mo wá ní iwájú pátápátá ó dáhùn, ó ni, ‘Jẹ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ rẹ́ ki n má ba pa ọ. Bí o ti wí báyìí ṣe ni mo déédéé rí ètè mi tí o ń sọ̀rọ̀ láìjẹ́ pé mo rán an, tí o sì sọ gbogbo ẹ̀sẹ̀ tí mo ti sẹ̀ láti ọjọ́ tí mo ti dé inú ayé, ọjọ́ tí mo bu ẹnìkan, lọ́jọ́ tí mo sẹ èpò, lọ́jọ́ ti mo bínú, lọ́jọ́ ti mo purọ́, gbogbo rẹ̀ ni ètè mi ń sọ, ìgbà tí o sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ i sọ, ẹni tí o gbé àáké yìí ní ki ń bọ́ sí èyìn òun. Lẹ́yìn náà, okan Ayédèrú-ẹ̀dá, ìgbà ti ètè Ayédèrú-ẹ̀dà bbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, kò sí ẹni tí àyà rẹ̀ kò já nínú wa. Ó ni, ‘láti kékeré ni ìyá mi ti maa ń rán mi lọ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ ki n bà le wá máa ṣe ofófó fún òun. Èmi ni ìyá mi rán lọ da májèlé sínú ọbe orogun rẹ̀ tí orogun fi kú, èmi ni ìyá mi fi obí oogun rán sí àbúrò rẹ̀ tí àbúrò rẹ̀ fi jáde láyé, èmi ni mo dá ìja sílẹ̀ láàrin àwọn ìjòyè ìlú wa tí gbogbo wọn fi da ẹ̀yìn kọ ara wọn. Èmi náà ni mo pa ìyá mi ki n ba jogún owo rẹ̀, ìbọn ni mo yin sí bàbá mi ti mo pa á. Ìgbà tí ọ̀rọ̀ òkè Ìrònú kanlẹ̀, mo ná owó fún Ìrìnkèrindò àti àwọn tí ó bá a wá sí ìlú wa kí ó ba à lè fún mi ni ipò ńlá. Ṣùgbọ́n ipó tí ó fún mi kko tíì tẹ́ mi lọ́rùn, ipó tirẹ̀ gan-an ló wù mi. Ẹ̀ẹ̀meje ni mo pinnu àti pa Ìrìnkèrindò tí ko ṣe é ṣe. Mo fi oogun sínu omi fun un lẹ́ẹ̀mejì, ko mu ú, mo fi májèlé sínú ẹmu, kò mu ẹmu náà. Mo fi ènìyàn sọ ọ kí wọ́n yìnbọn lù ú lẹ́ẹ̀mẹta, wọ́n yìn ín, ṣùgbọ́n kò bá a, nígbẹ̀yìn, òun pàápàá pa Ojúayédùn ti mo tún ni kí ó ba mi yìnbọn ní ẹ̀ẹ̀kẹrin. Èmi ni mo wí fún un pé ìyàwó rẹ̀ ń bá ẹlòmíràn jáde ní alaalẹ̀, èmi náà tí mo fi i si ibi kan kí ó máa wo ìyàwó rẹ̀ bí o ti ń ṣe pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn ni mo ni kí àbúrò ìyàwó rẹ̀ wọ aṣọ ìyàwó rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni emi ni mo yí aṣọ pada tí mo lọ bá àbúrò yìí. Ìyàwó Ìrìnkèrindò wọ̀ mi lójú púpọ̀, ojoojúmọ ni mo sì ń fẹ́ kí Ìrìnkèrìndò kú kí ìyàwó rẹ̀ di tèmi. Ìgbà kan mo ń fẹ́ fi ọwọ́ gbá ìyàwó rẹ̀ ní ìdí, bí mo sì ti ní ki ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ni ọwọ́ mi rọ, àti ọjọ́ náà ni ọwọ mi ti dí rírọ di òní abbl. Ìgbà tí ètè Ayédèrúẹ̀dá dákẹ́ ọ̀rọ̀ i sọ, ojú tìí púpọ̀, nǹkan tí ó burú níbẹ̀ ni pé ẹnikẹ́ni kò lágbára lórí ètè rẹ̀, ètè ń tìkararẹ̀ sọ̀rọ̀ ni, ìbá ṣe pé ènìyàn lè kìlọ̀ díẹ̀ fún ètè ni, ayédèrú-ẹ̀dá ìbá ti kilọ́ fún tirẹ̀. Ẹnú ya àwọn ọdẹ láti gbọ́ ohun tí ètè ọkùnrin náà sọ. Lẹ́yìn èyí, àwọn ẹlòmíràn tún kọjá tí ètè wọn tún sọ̀rọ̀. Kò sí ohun tí etí kò gbọ́ tán. Àṣe olè àti apànìyàn wà láàrin wa tó bẹ́ẹ̀! Àwọn tí a fi dá ọmọ ọlọ́mọ lóró sẹ́yìn kò mọ ní ìba. Lẹ́yìn tí gbogbo wa wa jẹ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ tán báyìí ni ọkuǹrin ti o gbé àáké lọ́wọ́ ní kí a máa kọjá lórí afá odò Ẹ̀jẹ̀. Irin kan ṣoṣo ni afá náà jẹ́, orí irun kékeré yìí ni olúwarẹ̀ sì níláti tẹ̀ kọjá. Ìgbà tí ènìyàn bá sì tilẹ̀ dúrósí etí odò Ọ̀jọ̀ pàápàá báyìí tí ó wo inú odò, ohun tí ojú rí kò mọ nìba. Odò yìí kkún fún ogunlọ́gọ̀ ènìyàn tí wọ́n ti já síbẹ̀ láti orí afá, èyí tí o sì ya ni lẹ́nu níbẹ̀ jù nipé wọn kò kú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n n mu omi odò Ẹ̀jẹ̀ báyìí lémọléemọ, ṣùgbọ́n wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ púpọ̀, ìgbà tí àwọn tí ó bá yọjú sí ìta bá fi ara hàn fún ìgbà pípẹ́ wọ́n a tún rì sí ìsàlẹ̀ kí wọ́n bá fún àwọn tí ó wà ní ìsàlẹ̀ odò ni ààyè kí àwọn náà tún wa sí òkè kí wọ́n fi ara hàn díẹ̀ kkí àwọn náà tún mu omi ẹ̀jẹ̀ lójú gbogbo aráyé. Bí olúkúlùkù ti ń mu omi Ẹ̀jẹ̀ lo ń kígbe sókè ti o tún ń dárúkọ ọ̀sọ̀ tí òun ti ṣẹ̀ sẹ́yìn. Ìgbà mìíràn, ẹranko buruku mìíràn a sa sí ẹlòmíìran a gé apá rẹ̀ kan kúrò lójù gbogbo wa, a máa jẹ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó ni apá kò ni kú, a o sì máa wò ó ti oun ti kùkùté tí ó kù tí yóò máa kígbe nínú odò náà. Èmi ni mo kọ́ bọ́ sí orí afá odò Ẹ̀jẹ̀. Mo tilẹ̀ rò pé n o já sínú odò Ẹ̀jẹ̀ náà ni, àfi ìgbà tí mo sì gbé ẹṣẹ̀ lé irin tí ẹṣẹ̀ mi fe méjéèjì ń gbé ara wọn láìjẹ́ pé mo gbé wọn, bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀, mo kọjá sí òdì kejì. Ìgbà tí Ayédèru-ẹ̀dá ń bọ̀, bí ó ti dé ìdajì afá gan-an ni irin dá sí méjì tí ó já sínú odò, wéré bí o ti dé inu odò ni a sì rí ẹranko kan sáré si i, ojú wa báyìí sì ni ẹranko náà ṣe gé apa rẹ̀ kúrò tí o gbé apá ha ẹnu tí o ń jẹ apa náà tí Ayédèrú-ẹ̀dá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé kùkùté apá kiri odò Ẹ̀jẹ̀ tí o ń kígbe. Bí Ayédèrú ẹ̀dá ti já bọ sí odò tán ni a fá tí ó dá ti o tún sopọ̀, púpọ̀ nínú àwọn sì dé òdì kejì ní àlàáfíà. Ìbẹ̀ǹbẹ́ olókùnrùn pàápàá kò ní ìpalára, a jọ gòkè ni. Ṣùgbọ́n ọ̀ppọ̀lọpọ̀ ló kú sínú odò Ẹ̀jẹ̀ nínú àwọn ti a jọ̀ n bọ̀, àti pàápàá àwọn tí wọ́n dára pọ̀ mọ́ wa láti ìlú àwọn aláṣejù. Ṣùgbọ́n bí àwọn Èdìdàrẹ́ ti gọ̀ tó nì, kò sí ẹyọ kan nínú àwọn tí o bá ni kúrò nínú ìlú wọn tí o jẹ́ pé ó kú sínú odò Ẹ̀jẹ̀, gbogbo wọn ni wọ́n dé òdì kejì dáadáa. Ewé-ẹ̀yẹ tí o tilẹ̀ jẹ́ olóògùn dáadáa kò kú sí odò Ẹ̀jẹ̀. Ìgbà tí ètè rẹ tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀, kò jẹ́wọ́ pé Ewe-ẹ̀yẹ pa ènìyàn rí tàbí kí ó ṣe ẹnikẹ́ni ní ibi. Nígbà tí a gòkè tán tí mo ka iye awa tí kò kú sínú odò náà, a jẹ́ àádọ́jọ, àwọn tí ó kú dàbí ọgọ́rùn-ún. Ko pẹ́ púpọ̀ tí a gòkè tan tí mo ṣe ìpàdé kí a bà yan ènìyàn sí àwọn ipò pàtàkì tí ó ṣófo lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti kú tán. Pẹ̀lú ayọ̀ ni àwọn ọdẹ fi yan Inúlayéwà sí ipò Ayédèrú-ẹ̀dá, tí o di pe oun ni igbá kejì mi. Ọlẹ́gbọ́n ni ọkùnrin náà, o sì jẹ́ oníwà rere. Nísisì yìí tí a ti kọjá odò Ẹ̀jẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kejì, àwa náà mọ̀ pé à ń súnmọ́ Igbó Elégbèje. A rìn tó wákàtí mẹ́ta sí odò Ẹ̀jẹ̀ nígbà tí a rii pé Ọ̀ nà túbi si i ti ojú ọ̀nà náà kún fún yanrìn funfun lọ gbáà, wọ́n gbá ojú ọ̀nà yìí ó mọ tingín tingín àwọn igi ńlá gbogbo ti wọ́n dàbí àràbà mi wọn sì wà ní apá ọ̀tún àti apa òsì lọ, ṣùgbọ́n, àti ewé, àti ẹka igi àti ìtànná àwọn igi wọ̀n-ọnnì, ṣe ni wọ́n funfun balau, inú igbó náà sì mọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé bí ènìyàn bá wo abẹ́ igbó báyìí, ènìyàn lè rí to irin bí wákàtí kan lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Àkíyèsí kan tí a bẹ̀rẹ̀ sii ṣe ni pé ìgbà tí a ba ń wo iwájú tí a ri tí ẹnìkan ń bọ̀ lọ́dọ̀ wa, ìgbà tí ó bá ṣe, a kò tún ní rí olúwarẹ̀ mọ́, ìgbà tí a bá sì maa wo ẹ̀yìn, a o ri i pé olúwarẹ̀ ti kọjá sẹ̀yìn wa. Ìgbà ó pẹ́ ṣa a rí ẹnìkan tí ó wí pé: káàbọ̀, Ìrìnkèrindò, ẹ múra, àwọn ẹranko ń fẹ́ bá yín jagun. OGUN IBODÈ IGBÓ ELÉGBÈJE B áyìí nim ọkùnrin náà wí, mo sì ń fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ ki n túbọ̀ wádìí nípa nǹkan tí o sọ, ṣùgbọ́n, wéré ló kọjú kò dúró mọ. Ìgbà tí ó ṣe, a yọ sí Igbo Elégbèjè. Nǹkan tí a kọ́ ṣe àkíyèsí ni ọ̀wọ̀n ńlá kan tí ó bá ojú ọ̀run lọ, tí o ddúró ní ẹnu ọ̀nà igbo náà. Ìgbà tí o ba ṣe tí a bá wo òkè ọ̀wọ̀n yìí, a dàbí ojú ènìyàn. Ti ó bá tún ṣe, a dàbí ojú kìnìhún, ìgbà tí o tún ṣe, a dàbí ojú ẹkùn. Bí ó bá tún yí padà á dàbí ejò ńlá, a máa yọ ahọ́n jáde bérébéré lẹ́nu. Ó tó ba ni lẹ́rù, ó tó nǹkan ti o lè lé ènìyàn padà. Igbó Ẹlégbèje pàápàá ba ní lẹ́rù, tó ti a ba ń wò ó bọ̀ níwájú. O dúdú tó bẹ́ẹ̀ ìtàkùn sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ igi gígga sì tún wà tó bẹ́ẹ̀ ti o ṣọ̀ro láti ṣe àpèjúwe. O ya ni lẹ́nu láti ri i pé wọ́n ṣe ilẹkun sí ẹnu ọ̀nà igbo náà, ṣùgbọ́n bí a ti n súnmọ́ ọ ni ìlẹ̀kùn ṣí fúnrarẹ̀ ti ẹnìkan kùǹtà báyìí jáde sí wa. Oun ni oníbodè Igbó Elégbèje, ó wọ sòkòtò péńpé kan báyìí, irun orí rẹ̀ gùn, o sì ba irun náà lọ si ẹ̀yìn, èyí ni nǹkan a nì bàrá ìdí bí o bá ń rìn lọ. Eyín ọkùnrin náà kò jọ ti ènìyàn rárá, o tẹ̀ kọ̀ọ̀lọ̀ kọ̀ọ̀lọ̀ o sì ba ni lẹ́rù bí ó bá ti ń sọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu, eyín náà pàápàá pupa o sì ba ni lẹ́rù. Bí a ti fẹ́ wọle ni ọkùnrin náà dá ni padà o ni a kò tí i gbọdọ wọlé, a níláti sùn niwájú igbó náà dí ọjọ́ kejì nítorí pé àwọn ẹranko àti ẹyẹ ti wí fún òun pé àwọn fẹ́ bá ni sọ̀rọ̀, bí àwọn bá lè pari ọ̀rọ̀ náà ẹ̀lú ìdẹ̀lọ́rùn àwọn kò ní ṣe nǹkan kan, ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn ó ba ni jagun. O tún wí pẹ̀lú pé a níláti wá oúnjẹ ti òun fún òun, ìgbà tí mo sì bèèrè ounjẹ rẹ̀, o ní ẹ̀jẹ̀ ni oun ń mu. Kò ì tíì pẹ́ ti ọ̀kan nínú wa pa àgbọ̀nrìn kan, a bá gbé e fún un. Ìgbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mo tí mo lọ sí ọdọ̀ oníbodè, o ránṣẹ́ sí ọ̀gágun àwọn ẹranko ẹni ti ń jẹ Ìnàkí-ìbẹ̀rù. Nígbà tí mo rí Ìnàkí-ìbẹ̀rù ẹ̀rù bà mi. O ni orí àti ojú tí o dàbí ti ènìyàn gan-an, bí ènìyàn lo sì ṣe ń sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́nláti èjìká sí isalẹ pátápátá, ti ìnàkí ni. Bí ó ba ń sọ̀rọ̀, ojú rẹ a máa pupa wẹ̀ẹ̀, díẹ̀ díẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ sì máa ń jáde. Màrìwò ọ̀pẹ ni Ìnàkí-ìbẹ̀rù sán mọ́ ìdí. Láti orúnkún sì lọ dé ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ó to ẹ̀gbà idẹ sí, àwọn ẹ̀gbà idẹ yìí tó bii méédogun ni ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Bí o ti ń rìn bọ̀, o kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ kùmọ̀ sí ọwọ́ òsì. Nígbà tí ó rí oníbodè, o rẹ́rìn-ín si i, ṣùgbọ́n ìgbà tí ó rí mi, o fa ojú ro, ó bẹ̀rẹ̀ síí sọ̀rọ̀ ó ni: Èmi ni Ìnàkí-ìbẹ̀rù tíí ṣe olórí ogun àwọn ẹranko, mo wa ni orúkọ gbogbo àwọn ẹranko, ti ẹyẹ, tí ẹja, ti ejò àti ti àwọn igi láti fi ẹ̀sùn sùn yín. Àwọn ẹranko ni àwọn ti gbọ́ bi ẹ ti ń pa àwọn ọmọ àwọn, tí kì í ṣe èyí tí ó dàgbà nínú wọn nìkan ni ẹ̀ ń pa jẹ, ti ẹ̀ ń pa èyí ti wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí lóòjọ́, èyí ti ko ju ọjọ́ méjì àti ẹranko ọlọ́jọ́ mẹta. Wọ́n ni ìwà tí àwọn tí ó ṣáájú yin hù ní ìlú àwọn kò tẹ́ àwọn lọ́rùn, àwọn Àkàrà-oogun fi ojú àwọn rí nnǹkan. Àwọn ẹyẹ ni àwọn ti mọ̀ bí ẹ̀yin ọmọ ènìyàn ti n mu ọmọ àwọn, ọ̀kan nínú wọn ti a ń pè ni kàkó gbóyà to bẹ́ẹ̀ tí ó gbá ọba àwọn lórí, orí ọba Aláyélúwà. Ògòǹgò baba ẹyẹ! Àwọn ẹja royìn ìwà ìkà yín sí wọn, bí ó ti jẹ́ pé àti kékeré àti ńlá nínú àwọn ni ẹ̀ ń fi àwọn kò kúrò nínú omi, ti ẹ kò tilẹ̀ dákẹ́ bẹ́ẹ̀, ti ẹ̀ ń jẹ ẹyín tí àwọn bá yé tí ẹ kò fẹ́ kí ìran àwọn sí nínú odò mọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni igi àti àwọn ejò ròyìn ìwà búbburú yin. Nítorí náà, ẹyin ọmọ ènìyàn, àwọn ọmọ ogun mi ti pé jọ ni onírúurú: kìnìhún kò níye, kò sì ẹni tí ó lè ka àwọn ẹkùn, ikooko pọ̀ lọ yanturu, Egbèje Erinmi lo n dúró bí ọmọ ogun àwọn ẹja, ọká àti erè la ẹnu sílẹ̀ dè yín hanha, àwọn igi tí kò le kúrò lójù kan ti ran àwọn iwin to ń gbe inú wọn wá jà lórúkọ igi, iwin inú ìrókò, iwin inuawusa, iwin inu ìbẹ́pẹ gbogbo àwọn iwin wọ̀nyí n dúró dè yín. Wọ́n ní ki n jíṣẹ́ báyìí fún yín, pé bí ẹ kò bá fẹ́ ìjà, kí ẹ ko àwọn ìbọn ọwọ yín jọ kí ẹ kó wọn fún oníbodè Elégbèje kí ó tó di agogo mẹ́jọ àbọ̀ òwúrọ̀ ọla, bí ẹ bá ṣe ijàǹbá, wọn ni àwọn ó jẹ́ kí ẹ lọ sí òkè Ìrònù láìsí ìjà láìsí ìpalára. Ẹnikẹ́ni kò ni fi ọwọ́ kàn yín, wọ́n ni àwọn ó mọ̀ pé ẹ kò fẹ́ láti ṣe ibi. Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá ṣe èyí, wọ́n ni ogun yóò bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn àti ẹ̀yin ni agogo mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ọ̀la. Báyìí ni olórí-ogun àwọn ẹ̀dá alaàyè wọ̀n-ọnnì sọ, ọ̀gbẹ́ni Ìnàkí-ìbẹ̀rù. Bí o sì ti dákẹ́ ni a gbọ́ ti àwọn igi pariwo, ti wọ́n ké báyìí pé, ‘o ṣeun, bi a ti ran ọ lo jíṣẹ́’. Lẹ́yìn tí ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, mo wí fún uun pé àwọn ènìyàn mi yóò lọ ro ohun tí o wí a o sì sọ ohun tí a fẹ́ṣe fún Oníbodè Igbó Elégbèje. Nígbà tí a ṣe ìpàdé, àwọn tí o ní kí a kó ìbọn wa fún Onibode Igbo Elégbèje kò ju mẹ́wàá lọ, gbogbbo àwọn ìyókù ni ó wí pé kí a pinnu láti jagun. Nítorí èyí, mo lọ sí ọdọ Oníbodè ni agogo mẹ́jọ mo sì sọ fún un pé a ò níí kó ìbọn ọwọ wa sílẹ̀ kí o sọ fún Ìnàkí-ìbẹ̀rù kí wọ́n múra fun ogun. Nígbà ti mo máa ṣe ètò ogun náà, fún àwọn ènìyàn mi, mo fi àwọn ti mo rò pé wọ́n jẹ́ akọni sí apá ọ̀tún, mo sì fi àwọn akoni sí apá òsì, àwọn tí mo rò pé wọn kò lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ ni mo ni kí ó dúró sí aarin èrò mi ni pé àwọn tí o wà lápá ọ̀tún àti apa òsì yóò ṣẹ́gun nígbà tí àwọn ẹranko ba gbá iwaju àti ẹ̀yìn yọ, kí wọ́n sì ti ipa bẹ́ẹ̀ yí àwọn ọmọ ogun ẹranko po, kí wọ́n fi àwọn ẹranko sí aarin. Àwọnẹranko ṣe ètò wọn ni ọ̀nà tí ó ya ni lẹnu. Ti pé àwọn iggi sì wà lẹ́yìn wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ púpọ̀, nítorí pé nígbà tí ìjà kọ́ bẹ̀rẹ̀ tí a wọnu Igbó Elégbèje tán àṣé inú àwọn igi tí ó wá lẹ́yìn wa ni àwọn wọ̀nyí lo máa ń kọrin nígbà tí wọ́n ba ń Ọlọ́run lógo, wwọn kò sì jagun. Bí a ti wọ inú Igbó ni a déedée gbọ orin lẹ́yìn wa, orin náà dùn tó bẹ́ẹ̀, o sì gba gbogbo àgbègbè tó bẹ́ẹ̀ ti a ṣebi ogun ń bọ̀ lẹ́ẹ̀yìn wa ni. Eléyìí kò jẹ́ kí á tètè jà bí o ti yẹ. Ìgbà tí o ṣe ni a rí àwọn ọmọ ogun èranko níwájú wa. Bí wọ́n ti ṣe ètò wọn kò rí bí awa ti rò. ṣe àwa ti rò pé àwọn ẹranko bii kìnìhúnm ẹkun, ìkookò, erin àti àwọn alágbára gbogbo ni yóò wà níwájú ogun, ṣùgbọ̀n kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Àwọn èkúté ni wọ́n ṣáa’jú, láàrin àwọn èekúuté yìí pẹ̀lú, ẹ̀lírí kkékeré ni aṣáájú pátápátá. Ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn wo wọ́n bí ọ̀kẹ́ àìmọye, ti ìbọn kò ṣe é fi pa wọ́n, ti ó sá jẹ́ pá wọ́n ń ge ni lẹ́sẹ̀ jẹ ni, ìbà díẹ̀ ni a lè ṣe. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ àti akèrè ti wọn jẹ ọ̀kan nínú àwọn ti ń jà fún ẹja pàápàá tún ddà wa láàmú, níto’ri pé igbe wọn lásán họ ọ, họ ọ, họ ọ, tí gba gbogbo àgbègbè tó bẹ́ẹ̀ tí a ko lè sọ̀rọ̀ sí ara wa, nígbà tí mo ba sì pàṣẹ fún àwọn ọdẹ igbe àwọn wọ̀nyí kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbọ́ ohun tí mo ṣo. A lo kùmọ̀ títí ṣùgbọ́n àwọn èkúté wọ̀nyí ti pọ̀ ju, ko sì sí nǹkan tí a le ṣe titi ilẹ̀ fi ṣu lọ́jọ́ náà. Kí ìjà tó bẹ̀rẹ̀, Ìnàkí-ìbẹ̀rù ti wí fún ni pé ìgbà tí ìjà bá parí lálẹ̀ ọjọ́ náà, àwọn ẹranko ń fẹ́ kí a bá àwọn jẹun. Ìgbà tí ilẹ̀ ṣú, a lọ aíle oúnj, ìyàlẹ́nu ló sì jẹ́ ti a ri tí wọ́n tẹ́ tabili lọ gbọọrọ, tí wọ́n ko ṣíbí fàdákà àti àwo fàdákà sílẹ̀ fún ni láti jẹun. Àwọn iwin ni àwọn ẹranko gbà ni aláṣè, àwọn ni ó sì ṣe gbogbo ìtọ́jú ti wọn ṣe. Wọ́n ni kí Ìnàkí-ìbẹ̀rù jókòó sí ìparí tabili ni apá kan, wọ́n ní kí emi náà jókòó sí ìparí ní apa kejì ki ń kọjú si i. Ó wá jẹ pé òun ni alága lálẹ́ ọjọ́ náà. A à bá gbádùn oùnjẹ náà dáadáa bí kò ṣe àwọn iwin tí ó bá wa jẹun. Àwọn ọdẹ jókòó sí apá kan tábìlí lọ, àwọn iwin ló sì jòkòó kọjú sí wọn. Òmíràn ní ojú kan, òmíràn ní ẹnu sí igbá àyà, òmíràn kò ní imú rarta, ojú òmíràn gùn ó dàbí ojú ìṣaasùn, ọrùn òmíràn gùn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó dàbí igi gíga lẹ́gbẹ̀ẹ́ tábìlí, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọn ni wọ́n ń fẹ́ bá àwọn ọdẹ sọ̀rọ̀ kí wọ́n bá wọn ṣe àwàdà. ọ̀tọ̀ ni àwọn ẹranko jókòó sí tí wọ́n ti ń jẹun nítoiríìdí wọn gongo gongo kò lè jókòó lé orí àga. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, ogun tún bẹ̀rẹ̀, àwọn ẹyẹ wọ́n ja ìjà ọjọ́ kejì ní pátákí kìí ṣe àwọn ẹyẹ ńlá bí aṣdi, agbe tábì àlùkò ni wọ́n bá wa jà. Àwọn ẹyẹ tí wọ́n wá sí ojú ìjà kò ju èkùrọ́ lọ, ìgbà ti wọ́n bá sì fò dé, wọ́n á bà lé ni lápá, lẹ́sẹ̀, ni góngó imú àti ni ibikibi lójú bẹ́ẹ̀ ni kò sí bi a ti ń pa wọ́n to tí a ri wọn gbé ṣe, bí ọ̀kan ti ń kú ni ekejì ń fò dípò rẹ̀, ọ̀ràn náà sì buru tó bẹ́ẹ̀ tí púpọ̀ nínú àwọn ọdẹ kò tilẹ̀ rí àyè gbé ibọn, ọwọ́ ló kù tí wọ́n fi ń jagun. Nígbà tì a lọ jẹun lálẹ́, àwọn ẹranko dá àbá pé ìjàkadì ni kí a fi ṣe ti ọjọ́ kejì àti wí pé àwa ti a jẹ́ olórí ni yóò jà kẹ́yìn lọ́jọ́ ìjàkadì yìí, èyí ni èmi àti Ìnàkí-ìbẹ̀rù. Ki n má tàn yín jẹ, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé awa ọpdé pàtẹ́wọ́ nígbà tí wọ́n sọ bẹ́ẹ̀, bí ẹni pé ó dùn mọ́ wa nínú, síbẹ̀ àyà olúkúlùkù já láti bá ẹranko jà. Ṣùgbọ́n níggbà tí àwọn ẹranko tún ṣe àlàyé pé àwọn iwin ni yóò bá àwọn ọẹ jà àti pé ìjà èmi àti Ìnàkí-ìbẹ̀rù ni yóò jẹ́ ìjà láàrin ènìyàn àti asoju Ẹranko, a pinnu láti sa ipá wa. Mo rò pé ẹ mọ̀ pé baba àti ìya mi ti ku àti pé àwọn mejeeji ko sí nínú ayé mọ́ lákòókò tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, ìyàwó mi ti fi mi sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà sì ti mọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì ẹni tí mo lè bá gbèrò lákòókò náà bí kò ṣe Inúlayéwà igbá kejì mi. Ṣùgbọ́n bí mo ti sùn lóru ọjọ́ náà nínú àgọ́ tí àwọn ọdẹ ṣe fún mi, ni èmí náà déedée wọlé tí ó jí mi. Ìgbà tí mo sì dìde, mo ri i ó di bàbá mi. Àyà mi kó já, ṣùgbọ́n bí ó ti na ọwọ́, tí ó wí báyìí: ‘Àlááfíà’ ṣe ni ọkan mi balẹ̀. O gbé ìgò kan fún mi oyin ni ó wà nínú ìgò náà, o ní kí ń fi ọwọ́ bà á, ki n tọ sí ẹnu, mo sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó tún wí fún mi pé igba tí ilẹ̀ bá mọ́ ki n gbe fún àwọn ènìyàn mi kí wọ́n tọ́ oyin inú rẹ̀ sí ẹnu. O ni, agbára oyin náà ni pe a o lè yí ara wa padà sí ohun kóhun tí a bá fẹ́ nígbà tí ìjàkadì bá le ni ọjọ́ kejì. Bbí ẹnìkan bá fẹ́ kí òun yípadà sí ọ̀bọ, bí o ba ṣa ti lè wí báyìí pe, ‘Emi ọbọ’ yóò di ọbọ wéréwéré, bí ó bá wí pe, ‘Emi òjòlá’, wéréwéré ni yóò di ejò ti yóò máa wọ́ kiri. Lẹ́yìn tí o ti wí báyìí fún mi tán, o ki mi pé ó dìgbà, n kò sì ri i mọ. Nígbà tí ilẹ̀ mọ, mo pe àwọn ènìyàn mi, mo rò fún wọn, olúkúlùkù sì tọ́ nínú oyin yìí lá. Lẹ́yìn èyí, a múra o dí ibi ìjà. Bí a ti ń lọ, afi ìgbà tí a déedée ń gbọ́ ìlù bàtá láàrin igbó yìí, wọ́n ń lúù tẹ̀lé Ìnàkí-ìbẹ̀rù, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ tí bàtá ń wí báyìí, ‘Ìnàkí-ìbẹ̀rù, Ìnàkí-ìbẹ̀rù, òní ni, ọla kọ́, òní ni, ọla kọ́, òní ni ìjàkadì, òní ni ìjàkadì, Ìnàkí-ìbẹ̀rù, Ìnàkí-ìbẹ̀rù yí ọmọ ènìyàn bíríbírí, yí ọmọ ènìyàn kọ́rọ́kọ́rọ́, yí ọmọ kítíkítí, gbé wọn na lẹ̀ bámúbámú, kí wọ́n máa rá pálápálá, fòkúta gùn wọn ṣókíṣókí, kí wọ́n họra pátípátí. Ta ni baba wọn? Ta ni bab ènìyàn? Ta ni baba wọn? Ta ni baba àgbọ̀rín? Ta ni baba wọn? Ta ni baba Ìmàdò? Ta ni baba wọn? Ìwọ ni baba ewúrẹ́, ìwọ ni baba wọn, ìwọ ni baba ọmọdé, ìwọ ni baba wọn, ìwọ ni baba àgbà, ìwọ ni baba wọn, ìwọ ni baba ènìyàn, ìwọ ni baba wọn, ìwọ ni baba ènìyàn, ìwọ baba wọn abbl. Báyìí ni Ìnàkí-ìbẹ̀rù n bọ̀ lọ́jọ́ tí à ń wí yìí, òun àti àwọn iwin. Àwọn ẹranko àti ẹyẹ tí ó wá, wọ́n wá láti woran ni, àwọn iwin tí o ń lu ìlú fún ìnàkí-ìbẹ̀rù, bí ènìyàn gan-an ni wọ́n rí, bàtá tí wọ́n sì ń lù, bàtá gan-an ni. Nígbà ti wọ́n yọ sí ni, tí wọ́n dákẹ́ ìlù, wọ́n pejọ sí apá kan wọ́n sì wí fún mi ki ń yan ẹnìkan sí òde láàrin àwọn ènìyàn mi kí ó bá ẹnìkan nínú tiwọn j��. Mo bá yan ọkùnrin kan báyìí ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ kùkùté, tí ó jẹ́ alágbára tí ó sì mọ ọwọ́ ìjàkadì púpọ̀. Kùkùté kìí ṣe ẹni gíga, kúkúrú báyìí ni, o sì ki, bẹ́ẹ̀ ni igbá àyà rẹ̀ tó fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ fẹrẹgẹdẹ. Iwin tí wọ́n yàn kí o bá kùkùté jà ga ó sígbọnlẹ̀, ó sanra, o rí mùkùtùn, déẹ̀ sì ni kùkùté fi ga ju ìdí rẹ̀ lọ. Ìdíwọ́ ni eléyìí jẹ́ fún òun, ṣùgbọ́n ìrànlọ́wọ́ ni èyí jẹ́ fún kùkùté, níto’ri ọwọ rẹ̀ kò rí àyè bá kùkùté tí o ń ta gbúrúgbúrú kiri. Ìgbà tí ó ṣe ṣa, ó ki kùkùté lọ̀rùn mọ̀lẹ̀ ó gbe e sókè ni reti pé kí ọwọ́ òun rí àyè ba kùkùté lẹ́sẹ̀, kí ó da orí rẹ̀ kodò, kí ó na orí rẹ̀ mọ́ òkúta kàbitì kan, ṣùgbọ́n nígbà tí o ń gbé kùkùté lọ sí òkè, kí ó tó kọja ibi abẹ́yá rẹ̀, kùkùté lọ ẹsẹ̀ mọ́ ọ ni ibi ẹ̀yìn, o fa ẹbọra náà létì, ó lọ́ ọ dáadáa, ẹbòra yìí bá ke bí màlúù, ṣùgbọ́n Oníbodè pàtẹ́wa pé kí wọ́n ddáwọ́ dúd’ro, o sì bá kùkùté wí pé tí ó ba tún ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí òun ó wí pé ẹbọra ṣẹ́gun, n;itor;i pé ìjàkadì láṣán ni a wí pé kí kùkùté jà. Ìgbà tí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, kùkùté wá ọ̀nà ó so mọ́ ẹbọra náà ní ìdí, ibi tí o sì n tìí ká, ó tìí sínù kòtò kan báyìí, ẹbọra jìn si i, ó bá ṣubú, Oníbodè pàtẹ́wọ́ pé kùkùté ṣẹ́gun. Lẹ́yìn èyí, mo tún yan ẹlòmíràn sí òde. Eléyìí ni ẹni ti ń jẹ́ Ẹyin-Ológbò. Ó dùn mi pe n kò rí àyè ròyìn ìjà Ẹyin-ológbà fún yin, nítorí àkókò ń lọ. N kò ni lè ròyìn ìjà tèmi àti ti Ìnàkí-ìbẹ̀rù jù bẹ́ẹ̀ náà lọ pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n èyí tí o ṣe pátákí jùlọ nínú ìjà náà ni pe àwa ni a jà kẹ́yìn, ìgbà tí a jà titi ti a kò gbé ara wa wọ́nlẹ̀ Ìnàkí-ìbẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ si i yípadà sí orísìírísìí nǹkan láti bá mi jà èmi náà ń yípadà pẹ̀lú. Ìgbà tí ó yìpadà tí ó di erin, èmi kò di erin, ṣùgbọ́n mo ni ki egbé gbé mi lọ sí ẹ̀yìn erin, mo si ń gun Ìnàkí-ìbẹ̀rù kiri: ìgbà tí ó ṣe ó di ẹfọ̀n, o n fẹ́ fi iwo gun mi, ṣùgbọ́n emi yípadà mo di òkúta, ìgbà tí o sì gbá ìwo rẹ̀ mọ́ òkúta díẹ̀ ló kù kí ó dá. Nígbẹyìn ó di omi ńlá, ṣùgbọ́n èmi di òòrùn, mo bẹ̀rẹ̀ síi ràn kíkan kíkan, àwọn ọdẹ di ẹye wọn n fo lo sori igi. Àsẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, ìnàkí-ìbẹ̀rù túúbá ó ní mo ju òun lọ. Báyìí ni a pari ìjàkadì ọjọ́ náà. ṣùgbọ́n ogun kò pari rárá a sì dúró tó oṣu kan gbóko kí ogun tó pari. Onírúurú ọ̀nà ni a sì gbà ti a fi ń jagun náà lọ. Ní ọjọ̀ kan Ìrèke nìkan ni o fi fèrè rẹ̀ ṣe nǹkan àràmọ̀dà lójú ogun. Ó ti wí ní alẹ́ ọjọ́ kan fún àwọn ẹranko báyìí pé òun nnìkan ni wọ́n máa bá jà ní òwúrọ̀ ọjọ̀ kejì. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ lóòótọ́ Ìrèké mú fèrè rẹ̀ o ń fọn ọn. Wéré gbogbo ẹ̀dá alààyè bẹ̀rẹ̀ si i jó, erin jó titi ó tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹranko pa, àwọn ọbọ jó wọ́n tàkìtì àti iwin àti ọdẹ bẹ̀rẹ̀ sii gbé onírúurú ẹsẹ̀ ijó lójú oggun. Ijó ni gbogbo ẹda alààyè jo titi ti ilẹ̀ fi ṣu ko. Ìgbà tí ó ṣe lẹ́yìn èyí, Kùmọ́dìran náà ń fẹ́ fi ara wé Ìrèké òun náà tún wí fún àwọn ẹranko pé oun ni kí gbogbo wọn nà ní kùmọ́ titi ilẹ̀ ọjọ́ kejì fi maa ṣu, òun ni òun fẹ́ kí àwọn ẹranko bá jà lọ́jọ́ náà. Lóòótọ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko àti iwin ṣe, ṣùgbọ́n Kùmọ́dìran ti ṣe àṣejù, lóòótọ́ ni ìsẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ èyí tí bí wọn kò bá nà an ní kùmọ̀ ara rẹ̀ kìí le, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò nà án ni kùmọ̀ tó ogojì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo rí. ní ọjọ́ ti à ń wí yìí, kùmọ̀ tí àwọn iwin na Kùmọ́dìran tó ẹgbẹ̀ta, Kùmọ́dìran kú. Ṣùgbọ́n Ìbẹ̀ǹbẹ̀-olókùnrùn sàn nínú àìsàn rẹ̀ lọ́nà kín-ín-ní òun pàápàá ti ronú pìwàdà ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ àtijọ́ gbogbo níto’ri ó ba ẹni rere rìn. Ìgbà tí a sì pa ẹran púpọ̀ nígbà kan ó yó ní ìgbà kín-ín-ní ọjọ́ ayé rẹ̀. Lẹ́yìn èyí arii, ikùn rẹ̀ fà, àti ọjọ́ náà lo sì ti dàbí gbogbo ènìyàn tí o ń jẹun bí gbogbo ayé ti ń jẹun. Ṣùgbọ́n fún odidi oṣu kan, ni a fi ń ja ìjà yìí tí kò sí ẹni tí ó ṣẹ́gun ẹnì kejì, ọ̀ràn náà sì ń fẹ́ wá bọ́ sí ìtìjú fún àwọn ọdẹ. Nígbà tí o di ọjọ́ kan. Mo lọ kúnlẹ̀, mo ké sí Ọlọ́run, mo bẹ ẹ kí o maṣe jẹ́ kí ojú tì mi, mo ké tàánútàánú tó bẹ́ẹ̀ tí omi ń bọ́ lójú mi nígbà ti mo fi máa jáde. Nígbà tí o di òru ọjọ́ yìí ni ìyá mi ti isà òkú wá bá mi. Nígbà tí o dé, ó jí mi kalẹ̀, o kí mi dáadáa, o ni ko nn ma ṣe jẹ́ ki àyà mi já, n ó ṣẹ́gun àwọn ẹranko. O ni oun ti fọrọ aṣẹ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọba kí òun tó máa bọ̀, Ọlọ́run sì ti wí pé òun wà lẹ́yìn mi. Lẹ́yìn náà, o fún mi ni ẹyọ obì kan báyìí, o tún fún mi ni àwọn èso igi, o sì fún mi ni ẹyọ àgbàdo púpọ̀, o ni obi ìgbéraga, àgbàdo ìgberaga àti eso igberaga ni òun fún mi wọ̀n-ọnnì, ìgbà tí a bá jí, kí a fi obi ìgbéraga fún àwọn iwin jẹ, kí a fi àgbàdo ìgbéraga fún àwọn ẹyẹ, kí a sì fi èso ìgbéraga fún àwọn ẹranko. O ní bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀ a kò ní pẹ́ ṣẹ́gun. Ìgbà tí o wí báyìí tán, ìyá mi wọ inú ilẹ̀ lọ. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, mo lo àwọn nǹkan tí ìyá mi fún mi bí o ti wí. Wéré ni a rí àyípadà \. Iwin tí kò ní òun ni o ye kí o se Alága ìpàdé àwọn iwin, iwin olórí kan kò gbọ́ràn sí olórí mẹ́wàá lẹ́nu mọ́, ologbo wí pé òun lágbára ju ẹkùn lọ, ggbogbo àwọn ẹyẹ bẹ̀rẹ̀ sii wa sí ọdọ wa ní à Síírí, wọn n wí fún wa pá aawa ni a ó ṣẹ́gun, ẹyẹ ẹ̀gà lásán ń wí pé òun ni kí a fi ṣe alaga ni ìpàdé àwọn nígbà tí a bá ṣẹ́gun tan, ẹyẹ àṣádi kàn tóbi lásán ni. Òwìwí mu àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wá, o ní kí a bá òun ṣe e, ìgbà tí a bá ṣẹ́gun àwọn tán òun kò fẹ́ kí àdán bá òun rìn ní òru mọ́. Lékèélékèé ní kí a bá òun rẹ ọ̀kín sílẹ̀ níto’ri òun lẹwa ju ọ̀kín lọ, gbogbo ara òun ni o funfun daadaa, nítorí náà oun ni ki a fi jẹ́ baálẹ̀ àwọn ẹyẹ ti n gbé ilé. Báyìí ni gbogbo wọ́n ṣe ti wọn da ẹ̀yìn kọ ẹ̀yìn. Ogun tí a sì jà lẹ́yìn èyí, àwọn ẹyẹ àti ẹranko kò tẹriba fún Ìnàkí-ìbẹ̀rù mọ, wéré ni a ṣẹ́gun wọn. Ìgbà tí a sì parí ogun yìí, gan-an ran ni a lọ sí òkè Ìrònù. Ṣùgbọ́n nígbà tí a dé ìlú náà tan, ó ṣòro díẹ̀ fún ni kí á tó lè ka èso igi ìrònù. Igi náà wà nínú igbó ìgbàlẹ̀ kan tí ó wà ni téńté orí òkè tí à ń pè ní òkè Ìgbéega. Òkè yìí ṣòro láti gùn lọ tó bẹ́ẹ̀ tí mo níláti wí fún àwọn ènìyàn mi kí wọ́n jẹ́ kí èmi nìkan gùn ún lọ, ojú ni rí nǹkan ki n tó gun òkè náà dé orí. Ìgbà tí mo tilẹ̀ wá tún wọ inú igbó ibi ti igi ìrònú wà, nǹkan túbọ̀ le. Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ejo burúkú ayé yií ló pé sínú igbó náà tan, ọká, àti paramọ́lẹ̀ àti èjò olóró gbogbo ni wọ́n wà, bẹ́ẹ̀ ni igi ìrònù jẹ́ igi ẹlẹ́gùn-ún tí ó mú bí orí abẹ́rẹ́, ó sì ṣòro ki nn tó lè gùn ún dé orí. Ìgbà tí mo ka èso rẹ̀ kan, fàdákà ni gbogbo ara rẹ̀ jẹ́, ọ̀kan ṣoṣo yìí náà ni mo lè ká nítorí àwọn èerà olóró gbogbo ni wọ́n ń rìn mi ní ẹ̀gbẹ́ ti wọ́n ń já mi jẹ. Ìgbà tí mo ti ká èso kan, mo padà pẹ̀lú ayọ̀ mò ń lọ. Ṣùgbọ́n bí mo ti ní ki ń jáde nínú igbó náà ni mo pàdé ẹnìkan tí ó wọ aṣọ funfun tí o wí fun mi pé n kò i tíì parí iṣẹ mi tí ó yẹ ki n ṣe, nígbà tí mo sì bi í léèrè iṣẹ́ tí ó kù, ó ní èso igi ìrònú kò já mọ́ nnkan kàn àfi bí mo bá ká èso igi mìíràn tí à ń pè ni Ìfẹ̀yìntì-Olódùmarè pẹ̀lú rẹ̀. O ṣe àpèjúwe pé igi náà kò jìnà sí igi ti mo ti gùn. Ìgbà tí mo tún padà mo wa rí igi Ìfẹ̀yìntì-Olódùmarè yìí, ṣùgbọ́n ṣe ni ara rẹ̀ ń yọ̀ bí ilá ọ̀ọ̀meje ni mo sì já lulẹ̀ nibi tí mo ti ń gùn ún, nígbẹ̀yìn ṣá mo fi erùpẹ̀ ra inú, mo bẹ̀rẹ̀ sí í pọn ọn títí mo di dé òkè tí mo ká èso náà, góòlù ni gbogbo ara rẹ̀, ṣe ni o n pupa dẹ̀dẹ̀. Mo ba ko àwọn èso méjéèjì, mò ń bọ̀, bí mo sì ti j;ade sí ilú òké Ìrònú ni mo pàdé iwin kan tí ó ni ojú méje, tí ojú wọ̀n-ọnnì tò yi gbogbo agbárí rẹ̀ ká, òun ni ó mú ìwé kan fún mi. Ìgbà tí o ka ìwé náà, o dì ìwé tí ìyàwó mi kọ sí mi, o ni òun ti ń wo ìyà gbogbo tí mo ti jẹ láti ìgbà tí òun ti lọ, ìforítì mi jọ òun lójú gidigidi, òun kò le fi mi sílẹ̀ mọ́, òun dari gbogbo ohun ti mo ti ṣe jì mi, nítorí náà, ki n yà sí ọ̀dọ̀ òun nígbà tí a ba ń pada bọ̀. Kò sí ààyè nísisì yìí láti tún sọ gbogbo ohun tí oju wa rí lẹ́yìn ìgbà tí mo padà dé ọ̀dọ̀ àwọn ọdẹ tán titi a tún fi padà dé ìlú wa. Ṣùgbọ́n mo yà sí ọ̀dọ̀ ìyàwó mi nígbà ti a ń padà lọ sí ilé ní odo Ìràntí, o sì fi dúkìá rẹ̀ gbogbo hàn mi, o ni nǹkan tí ó dára ni pé ìgbà tí èmi àti àwọn ọdẹ bá padà dé ìlú wa, tí mo jíṣẹ́ fún ọba wa tán, ki ń padà wá sí ọ̀dọ̀ òun kí a jọ máa gbé aafin oun. Bẹ́ẹ̀ náà ni mo ṣe, ìgbà tí emi àti àwọn ọdẹ díẹ̀ tó kù padà dé ìlú wa, ọba wa tí ó ti darúgbó yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó fún wa ni ẹ̀bùn pùpọ̀, a sì tún fun un ni eso igi méjéèjì, èso igi ìrònú àti èso igi Ìfẹ̀yìntì-Olódùmarè, lẹ́yìn èyí, mo padà lọ sí ọdọ ìyàwó mi. Emi àti ìyàwó mi lo sì jọ ròó pé ki ń wá sí ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ mi yìí ki n sọ ìtàn ìgbésí ayé mi fún un. Àti pàápàá, bàbá mi ti pàṣẹ bẹ́ẹ̀ fún mi kí ó tó kú. Mo kí gbogbo yín láì ku ẹnìkan, o dìgbà díẹ̀ ná, onílé re ilé o. Báyìí ni ọkùnrin náà wí, bí o sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, a kò ri i mọ́. Ṣùgbọ́n ọkan nínú àwọn ọlọ́gbọ̀n tí wọ́n péjọ sí ilé mi tí wọ́n gbọ́ ìtàn náà wí fún mi pé rírí tí a kò rí ọkùnrin náàmọ́ kò ya òun lẹ́nu, nítorí kò yàtọ̀ sí Àkàrà-oògùn jú bẹ́ẹ̀ lọ, òun àti Òmúlẹ̀mófo ọ̀kan náà ni. Ọ̀rọ̀ ni ìwọ̀nyí, ẹ̀yin ènìyàn mi, àti pàápàá ẹ̀yin ọmọ ilé-ìwé, àti ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olúkọ́ wọn. Mo fi ìwọ́nyí wa. Bí ẹ bá ti ń rìn kiri nínú ayé, mo fẹ́ kí ẹ máa wo ohun gbogbo fínnífínní, kí ẹ fiyèsí ohun tí o gbé àwọn eni ìṣáájú ṣubú kí ẹ má ba à ṣubú bí wọn, kí ẹ sì wo iṣẹ́ tí ìforitì ń ṣe fún ọmọ ènìyàn, kí ẹ̀yin náà ba forítì ìṣoro yín. N ó parí ìwé ti eléyìí nísisì yìí, kí Ọlọ́run dá ẹ̀rú sí, a o tún máa gbúròó ara wa ní ọjọ́ mìíràn. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo yín o. Ilẹ̀ yín yóò dára ọ̀nà yín yóò sunwọ̀n, iwájú ni ẹ ó máa lọ, ẹ kò ní di èrò ẹ̀yìn, nǹkan yín kò ní bàjẹ́, rere ni ẹ o maa rí láéláé. ÌTUMỌ̀- Ọ̀RỌ̀ ÌṢÍNI-LÉTÍ L'àbáwọlé fáfitì kan ní Orílẹ̀-èdè South Africa, àwọn ọ̀rọ̀ ìṣínilétí wọ̀nyìí ni wọ́n kọ sóde fún àròjinlẹ̀: "Pípa Orílẹ̀-Èdè k'Órílẹ̀-Èdè run kò gba lílo àdó olóró tàbí àwọn ohun-èlò ìjà olóró alárìnjìnà. Ohun kan péré tó gbà ni dídẹwọ́ lórí ìkúnjú-òsùnwọ̀n ètò-ẹ̀kọ́ àti gbígba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láyè láti máa gbéégún nínú ìdánwò." Àwọn aláìsàn á máa kú lọ́wọ́ irú àwọn dókítà bẹ́ẹ̀. Ilé yóò dà wó lọ́wọ́ àwọn onímọ̀-ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀. Owó yóò di àwátì lọ́wọ́ àwọn onímọ̀- owó àti ọrọ-ajé bẹ́ẹ̀. Ìjẹ́-ọmọ-ènìyàn yóò kú lọ́wọ́ àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀. Ìdájọ́-òdodo yóò dàwátì lọ́wọ́ àwọn agbẹjọ́ro àti adájọ́ bẹ́ẹ̀... Ètò ìṣèlú yóò dojú rú lọ́wọ́ irú àwọn aṣòfin bẹ́ẹ̀. *"Ìfórísánpọ́n ètò- ẹ̀kọ́ ni ìfórísánpọ́n orílẹ̀-èdè."* Ìtumọ̀ sí èdè Yorùbá Ayọ̀ọlá Fádèyí láti ọwọ́ EWÌ - ÌDÁRÒ Adébọ́lá Pius Adésànmí (1972 - 2019) - Ayọ̀ọlá ọmọ Fádèyí Erin wó, gbogbo inú igbó pa kése Àjànàkú lọlẹ̀ wì, ọba ọ̀dàn ṣòjòjò Yemọja kú, ẹja kẹ́ja ò jẹ́ wẹ̀ nínú ibú Olóòlà òǹkọ̀wé re àjà, òjé ìkọ̀wé gbẹ fírí Wọ́n ni, kínni ìṣẹ́ tí àwọn tún gbà mọ́ Lẹ́yìn ikú olùbádámọ̀ràn àwọn Ó ṣe, ikú o ṣèyí tán! . Ẹni bá mọ ikú Kó bá mi béèrè lọ́wọ́ ikú oun mo ṣe fún - un Ẹni bá mọ Àsàráílù Kó bá mi béèrè lọwọ Àsàráílù oun mo fi ṣé Tó fi mú Adébọ́lá Àkànjí mi lọ A báni dámọ̀ràn bí ìyekàn ẹni Baba Tise, olówó orí Olúmúyìwáá . Lọ́jọ́ kan àná lo gbé ikú jẹ; o gbé ikú mì Lọ́nà Ògbómọ̀ṣọ́ sí Ọ̀yọ́ O ti àwọn ọ̀tá rẹ l'ójú O fi omi ata bọ̀wọ́n lójú Ikú ṣe wa padà mú ọ láìròtẹ́lẹ̀? Ìrìnàjò láti Addis Ababa sí Nairobi Ni àrìn-kẹ́yìn rẹ, àpérò Ilẹ̀ Áfíríkà lò ń lọ Iṣẹ́ rẹ lò ń ṣe rìnrìn àjò lọ́jọ́ burúkú yìí Ọjọ́ burúkú, ọjọ́ eṣu gbomimu Ọjọ́ burúkú, ọjọ́ ògún fẹ̀jẹ̀wẹ̀ Ọjọ́ kẹwàá oṣù Ẹrẹ́nà ọdún 2019 L'ọkọ̀ bàlúù tí o wọ̀ já pàù nínú afẹ́fẹ́ lókè lọ́hùn-ún Ẹ́tà dín l'ọ́jọ èèyàn ló ṣòfò ẹ̀mí l'ọ́jọ́ ẹlẹ́kọ ọ̀run ń polówó Kò sí eegun, kò sí èérún, ọmọ èèyàn pòórá mọ́lẹ̀ Ẹkùn, ìróra, ìkẹ́dùn gba ayé kan, nǹkan ṣe! . Ṣé wọ́n ní ikú dóró? Èmi ò mọ̀ p�� ikú á máa dá oró lóòótọ́ Béèyàn kú àfi kí n kíi pé ó dìgbà ó ṣe Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gba pe ikú ń dóró láì wẹ̀yìn wò Ṣé ẹni ikú pa kọ́ ló d'óró fún Àwọn èèyàn t'ókùú fi sílẹ̀ lọ nikú nà l'ẹ́gba ìpayínkeke Ikú dá oro yìí náà Ó wọ́mi déegun, ó wọ̀ ṣìnkun akínyẹmí ará mi lógán Ikú gbé òrònròó òun yèrèpè wọ agbárí mi lọ Gán-na-gàn-na l'ó kù tí n ò ṣe A ṣé báyìí nikú burú tó Ògidì ọmọ Adésànmí lọ . A-dú máa dán, ọrẹ ìmùlẹ̀ lórí Òpópónà 'Facebook' A fi ọ̀yàyà ṣòrọ̀, kí ọ̀ràn má bàa dunni A fẹ̀sọ̀ dá ìjọba l'ẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ A perí olóṣèlú kilọ̀ fún jẹgúdújẹrá wọn Á dá wọn lọ́wọ́ kọ́ gẹ́gẹ́ bí ọba sí ará ìlú Adébọ́lá ọmọ Adésànmí a-gùn-taṣọ̀ọ̀-lọ̀ Ojú rekete, ọkùnrin fàkàfíkí Ògbójú ọdẹ nínú igbó ìmọ̀ Ó fi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ fọ́kọ́ mú fún onílé Ó fi ọgbọ́n àgbà pògì mú fún àlejò Ṣẹnu róbótó pilẹ̀ ọ̀rọ̀ ìwúrí Bàbá afinú-ṣọgbọ́n rèwàlẹ̀ àsà . Gbogbo àwọn tí o fi ìmọ̀ rẹ jínkìn-ín l'Áfíríkà ń ṣe lé dè lẹ́yìn rẹ Gbogbo àgbààgbà Ilẹ̀ Yorùbá ní kí n máa kì ọ Gbogbo Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ilẹ̀ Kú-òórọ̀-oòjííre ni wọ́n ni kín n kí ọ Gbogbo ọba ládéládé Ilẹ̀ Odùduwà ní wọn ránmi sí ọ Ṣe tí onírèsé ò bá fíngbá mọ́, Èyí tó fín sílẹ̀ ò le parẹ́ Wọ́n ní ń fi dá ọ lójú pé Iṣẹ́, ìṣe àti ọ̀nà rẹ kò ní di àwátì Gbogbo rẹ ni àwọn yóò fọ́nká sí ibikíbi nílé ayé Tí ìrandíran ọmọ adáríhunrun yóò ma jẹ àǹfààní rẹ̀ To- lórí tẹlẹ́mù tọ̀kọ̀tùlùú ló pàwọ̀dà di dúdú fún ọ . Mọ̀mọ́ Bámidélé aya Ọlátẹ́jú, Bàbá Abímbọ́là Olújídé Ẹ kú ọ̀rọ̀ ìmùlẹ̀ yín tó di olóògbé Ìyáàfin Olúmúyìwáá Mama Tise, Ìyá Àgbà Mama Adébọ́lá Ẹ kú àmúmọ́ra tí ọkọ àti ọmọ yín Igi tó dá kìí pẹ́ nígbó Akọ igi kìí ṣe òjé Ẹ kú ọ̀rọ̀ ènìyàn Elédùmarè nìkan ṣo ló lè tù yín nínú Ẹ kú ilé dè . Tò, Elédùmarè, Ọba Ọ̀gá ògo Mo tẹ́wọ́ mi méjèèjì sí ọ Mo bẹ̀ ọ́ kí o foríji ẹni wà tó lọ Kí o pa àṣìṣe rẹ̀ rẹ́ Kí o gbà á sí àárín àwọn èèyàn réré l'ọ́run Kí o sì fi ikú wèrewère mọ lórí èyí Kí ó má ṣé ní sísẹ̀ntẹ̀lẹ̀ Ẹ̀yin ẹ̀ ń báni dáró Ikú Ọ̀jọ̀gbọ́n Adébọ́lá Pius Adésànmí kìí ṣe t'ọ̀fọ̀ Ká kú ní kékeré ṣ'àgbà ká dàgbà di ẹni yẹ̀yẹ́ . Tí kìí bá ṣe t'ikú Ọmọ Adésànmí ì bá fi gbòǹgbò jọ Baba Wọlé Ṣóyínká Ìjọba Nàìjíríà, ẹ wá ohun kan gbòógì fi sọri ọmọ Adésànmí Torí orúkọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ọmọ Alfred Adésànmí ti tàn ká Níti dáadáa pẹlu ìṣe ọpọlọ tó múyán lórí tó gbé ṣe Ẹ̀yin ọ̀jẹ̀lu Nàìjíríà, ẹ fi ìhùwàsí Adébọ́lá ṣe àkọ̀mọ̀nà Adébọ́lá Pius Adésànmí gbé lé ayé ṣe rere T'ẹ̀gàn lókù . ÀRÒKỌ OLÓWÓ-ÌBÍNÚ ÀTI ÌYÀWÓ-O RẸ̀ ÌDÀÀMÚ-AYÉ Ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi Olùkọ́ Èdè Yorùbá, Mo kí-i yín pẹ̀lẹ́ ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi àtàtá . Ẹ kú-u bí ojú ọjọ́ ti rí. Ṣé àwọn ènìyàn-àn mi wà ní àlàáfíà? Ìyàwó àti àwọn ọmọ nkọ́? Ṣe ẹ-ẹ̀ jà si ò-o. Mo rántí wí pé mo ṣe ìlérí kan fún-un yín láìpẹ́ ọjọ́. Àbúrò-ò mi Yínká Adébóyè kò tilẹ̀ jẹ́ kí nfi ẹ̀dọ̀ lórí òróṅro nítorí ìlérí náà. Yínká tilẹ̀ sọ fún mi wí pé ọjọ́ tí mo bá ti mú ìlérí-ì mi ṣẹ òun yóò ra ògidì ẹmu fún mi. Òun yóò se ọbẹ̀ tí ó jọjú kí njẹ-ẹ́ pẹ̀lú ẹran ìgalà àti iyán tí ó gbámúṣé; odidi ọ̀yà kan lòun yóò sì gbé fún mi relé lẹ́hìn tí mo bà gbádùn ara-à mi tán. Ènìyàn iyì ni àbúrò-ò mi Yínká; nítorí náà, bí mo fẹ́ bí mo kọ̀ mo ní láti sọ ìtàn tí mo ṣèlérí-i rẹ̀ fún-un yín. Ìtàn kan ni ó jẹ sí mi lọ́kàn lónìí yìí. Bàbá-à mi ni ό sì fi ìtàn náà tó mi létí kí n tó ní ìyàwó. Mo sì mọ̀ wí pé tí mo bá sọ ìtàn náà fún-un yín kò burú, bí a bá sì jọ gbádùn-un rẹ̀ kò léèwọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó le-è mú mi bí mo bá fi lu ìlù ògìdìgbó, tí ọlọ́gbọ́n bá bá mi jό-o tí ọ̀mọ̀ran sì bá mi mọ̀n-ọ́n. Bàbá-à mi ti kìlọ̀ fún mi wí pé ó yẹ ki nsọ́ra kí n tó ní ìyàwó, kí n sì kún fún àdúrà kí n tό lóbìnrin. Ó wí fún mi pé nṅkan ńlá ni ìgbéyàwó, ayẹyẹ ńlá sì ni ọjọ́ ìgbéyàwó pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní-í gbé ìyàwó níjọ́ tí olόde ńgbòde; wọ́n á gbé ìyàwó nínú ibú ìbìnújẹ́, wọ́n á fi Sàtánì ṣe ìmùlẹ̀, Bìlísì yóò bá wọn kẹ́sọ̀-ọ́ ròde, Wàhálà yóò sì jẹ́ ojúlówó èníyàn níjọ́ àjọyọ̀-ọ wọn. Bí bàbá-à mi sì ṣe sọ ìtàn yìí fún mi ni ń ò ṣe sọ́ fún-un yín lónìí yìí ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi. Ẹ jẹ́ ki nsọ ìtàn náà fún-un yín; kí njù-ú sí i yín bí àkàṣu èdè àti ọ̀rọ̀. Kí a sì jọ gbádùn ara wa bí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ tó rí ṅkan ayọ̀ yọ̀ sí. N όò jόkòό sí ipò-o bàbá-à mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi náà yόò sì jόkòό sí ipò mi bí mo bá ṣe ńsọ ìtàn náà fún fún-un yín. Kí èmi àti ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi sì gbàdùn ìtàn náà bí Ìbàdàn ṣe ńgbádùn ọkà àti ọ́ọ́yọ́ tòun ti gbẹ̀gìrì. Kí ìtàn náà wọ inú–un wa lọ, kí ó wọ inú ẹ̀jẹ̀-ẹ wa lọ kό ṣe wá ní àṅfàní; kí a sì jọ kọ́ ẹ̀kọ́ ti yóò ṣe ọmọ aráyé lόore. Ẹ bá mi kálọ ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi. Ọkùnrin olόwό kan-án wà ní ayé àtijọ́ tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Olόwό-Ìbínú. Bàbá tí ó sì bí-i ni Ìfòyà tí-í ṣe ọkọ Ìfẹ́dàrú ọmọ ilé Àìbalẹ̀-Ọkàn níbi tí Inúnibíni ti-í ṣe Mọ́gàjí-i wọn. Olόwό Ìbínú ló ní owó jùlọ jàkéjádò ìlú-u wọn ní àtijọ́. Tọmọdé tàgbà ló sì mọ̀ wí pé ní àgbàlá Olόwό-Ìbínú ni igi owó ti ńso. Oníṣòwò tí ó dáńgájá ni Olόwό-Ìbínú, ohun tí ó sì ń fi inú–un rẹ̀ rò ní ọ̀sán àti òru kò ju owό lọ. Owό ni èrò ọkàn Olόwό-Ìbínú ní ìgbà gbogbo, owó sì ni ό fẹ́ràn júlọ ní òde ayé. Olόwό-Ìbínú fẹ́ràn owó ju ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ. Olόwό-Ìbínú kì-í ṣe ohunkόhun láì ronú owó. Ní ìgbà tí ó sì tó fún-un láti ní obìnrin torí owó ló ṣe fẹ́ ìyàwó-o rẹ̀. Orúkọ ìyàwó-o rẹ̀ ni Ìdààmú-Ayé. Ìdààmú-Ayé sí ni àrẹ̀mọbìnrin Olόyè Ògbójú, Mọ́gàjí Ilé-Ìkà ní Ìlú Ìbàjẹ̀-Ènìyàn. Olόwό-Ìbínú fẹ́ obìnrin yìí nítorí ό rò wí pé tí àwọn àna òun bá kú, owó-o wọn yόò di ti òun ni. Ẹni líle ni Olόyè Ògbójú, Ọkùnrin náà sì gbóná ju àpáàrà lọ. Olόyè Ògbójú kò náání ẹnikẹ́ni lόde ayé, ό sì burú tό bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò sí ẹni tí ό ńsọ̀rọ̀ Ọkùnrin náà dára nílé lόko. Olόyè Ògbójú ti wό ilé aláìsàn rí nítorí onitọ̀un jẹ-ẹ́ ní kọ́bọ̀. Ò ti gba ibùsùn lọ́wọ́ aboyún rí nítorí ẹ̀kọ sísì; ό sì ti lu ọmọ òkú ọ̀run ní kùmọ̀ lόrí rí nítorí-i kúlíkúlí-i ṣílè kan. Ìtàn pàápàá sì sọ wí pé ní ìgbà tí Olόyè Ògbójú má-a fẹ́ ìyàwó-o rẹ̀, Ilé Alájẹjù lọ́dọ̀ Balόgun Ojúkòkòrò ọkọ Gbèsè lόti lọ m’obìnrin. Akọ́bi ilé náà tí ńjẹ́ Àdánwò ló sì fẹ́. Ó fi tìpá tìkúùkù gbé ọmọ náà láì san owó ori-i rẹ̀ ni. Ó ní awọn òbì-i rẹ̀ gba oko lọ́wọ́ òun ní pọ́ùn kan, wọn kò sì tí-ì sanwό oko tán. Ní ìgbà tí yόò sì ṣírò èlé orí oko, èlé owó tό ní kí wọ́n san ju àpò mẹ́fa lọ. Ṣé ajá tí yόò sọnú kì-í gbọ́ fèèrè ọdẹ. Gbogbo ènìyàn ni ό gba Olόwό-Ìbínú ní imọ̀ràn kí ό máṣe fẹ́ Ìdààmú-Ayé ṣùgbọ́n ό kọ̀ jalẹ̀. Olόwό-Ìbínú ní Ìdààmú-Ayé nìkan lό wu òun lóbìnrin. Tí àwọn bá si fẹ́ ara wọn kò léèwọ̀; owó wọn yόò má-a ṣubú lόrí owó, ọlá lόrí ọlá, ìgbéga wọn yόò sì má-a wà lόrí ìgbéga. O si da oun loju wí pé ni igba ti Olόyè Ògbójú bá pa ipò dà, gbogbo owó-o rẹ̀ yόò di ti Ìdààmú-Ayé. Níwọ̀n tí òun sì jẹ́ ọkọ Ìdààmú-Ayé, owó náà yόò di ti òun. Olόwό-Ìbínú àti Ìdààmú-Ayé ṣe ìgbéyàwό, ọjọ́ ìgbéyàwό-o wọn lárinrin púpọ̀, ayé gbọ́, ọ̀run sì mọ̀ pẹ̀lú wí pé àwọn gbajúmọ̀ méjì-í fẹ́ ara wọn. Ṣùgbọ́n àtẹ̀yìnwò ìgbéyàwó wọn kò ṣẹnure. Nítorí Ibú Ìbànújẹ́ ni wọ́n ti ṣe ìgbéyàwό, Ọ̀run Àpáàdì sì ni ìwé ẹ̀rì-i wọn-ọ́n ti jáde. Sàtánì ló jόkόό bí alága ìgbéyàwό, Bìlísì-í sì jόkòό sí ibi ẹ̀yẹ. Gbogbo eku-ú jẹjẹ jẹ wọ́n yó; àwọn ẹyẹ jẹ èso títì wọ́n fi orí sọgi. Elégbèdè mọtí yό ό lu igi mẹ̀fa ya, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀lírí ńgbádùn ayé-e rẹ̀ lẹ́bà-á àsun fún odidi oṣù mẹ́jọ láì fara pa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹni jàṅkàn jàṅkàn ló wá sí àṣeyẹ yìí; àwọn ẹ̀mí ọ̀run olόkìkí sì wá pẹ̀lú. Àwọn gbajúmọ̀ tό wá ńkíra kú àtijọ́. Àwọn mẹ̀kúnù jόkòό sí àyé wọn pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ láì b’Ólúwa wíjọ́. Àwọn ọ̀tọ̀kùlú sì ńṣe fàájì bí agbára-a wọ́n ti mọ. Ikú wá, òun àti ìyàwó-o rẹ̀ Àrùn. Àìní wá ṣùgbọ́n ìyàwó-o rẹ̀ Àkísà kò le-è wá nítorí Òṣì ọ̀rẹ́-ẹ rẹ̀ ńṣe ọjọ́ ìbí. Òun àti èkejì-i rẹ̀ Àbùkù lọ jόkòό sí ìta níbi tí wọn ti le-è tètè rí ońjẹ jẹ. Èṣù-ú pàápàá wà, Ẹlẹ́gbára náà sì wá pẹ̀lú. Ìrẹ̀lẹ̀-ẹ́ wá ati ọ̀rẹ́-ẹ rẹ̀ Ṣebíotimọ ṣùgbọ́n ariwo Ìgbéraga àti ìbátan rẹ̀ Àṣejù ti pọ̀ jù nítorí náà wọn kò pẹ́ púpọ̀ kí wọ́n tό-ό lọ; wọ́n lọ bá ọ̀re-ẹ́ wọn Ayọ̀ àti Inú-dídùn níbi ti wọ́n ti ńta ayò ní ìgboro. Ìnákúnàá ni alásè, bẹ́ẹ̀ ni àbúrò-o rẹ̀ Àwìn lό wà ní ìdí ọtí. Ọ̀gbẹ́ni Ẹ̀tàn ni ό ńdárin, Èké ló ńlu ìyá ìlú, Irọ́ sì ni ό ńlu omele. Ìranú ati Àìnírònú ńfi ọwọ́ kọ́ ara lọ́rùn nìbi tí Òfò ti ńṣe sisí, tí Àìbìkítà sí ńṣe ojúlόwό Ọkùnrin. Àwọn ará ilé Ọ̀tẹ̀ mú ìjόkòό ńlá, Olόyè Àbòsí sì jόkòό ní agbo ènìyàn pàtàkì pẹ̀lú ọ̀rẹ́-ẹ rẹ̀ Àgàbàgebè. Olùyà pọ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́, Ẹni-Ìyà sì pọ̀ láàárín ìbátan. Àìrόjú lό mú ìyàwó wọlé, Imẹ́lẹ́ ló fà-á lé ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ níbi tí Òfófó àti Owú ti jẹ́ Olόyè láàárín àwọn obìnrin, tí Ìnira sì jẹ́ ẹni iyì láàárín àwọn Ọkùnrin. Àwọn ẹni ńlá tí ó wá sí ìgbéyàwό yìí gbadun ara wọn pupọ̀. Oríṣiríṣi ẹ̀bùn ni wọ́n sì fi ta tọkọtaya yìí lọ́rẹ. Ẹní mú owó wá mú owó wá, èyìí tí ó fún wọn láṣọ-ọ́ fún wọn láṣọ. Tánńganran kúnlé gbári, ohun ọ̀sọ́ kò sì lóhùnkà. Ibi tí wọ́n sì kó ẹ̀bùn sí tóbi ju Gbọ̀ngàn-ìṣeré-òmìnira ti ìlú Ìbàdàn lọ. Ṣùgbọ́n ní gbogbo àwọn ẹ̀bùn tí àwọn tọkọtaya yìí gbà lọ́wọ́ àwọn tí ó yẹ́ wọn sí, kò sí èyí tí ó dára tó ibùsùn idẹ tí Bìlísì fi ta wọ́n lọ́rẹ. Ibùsùn yìí kò ní àfiwé; gbogbo ọ̀pá ibùsùn yìí la fi gόòlù ṣe ọnà sí lára. Omi díámọ́ṅdì la fi kọ orúkọ tọkọtaya sí ìgbèrí ibùsùn náà. Tìmùtìmù ìrọ̀rí-i rẹ̀-ẹ́ jẹ́ ti ẹ̀gbọ̀n òwú olόwó iyebíye; bẹ́ẹ̀ ni itẹ́lẹ̀-ẹ rẹ̀ dàbí àrán ọba pàtàkì. Ibùsùn náà dára ό wu ni jọjọ. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́-ẹ̀ mi tòótọ́, ẹ jẹ́ kí á sinmi ìtan dídùn yìí fún òní. Tí ó bá di ọ̀la, n ó-ò parí ìtàn náà fún-un yín Ó dàáro ná. Kí Olúwa jí wa’re Ire òó Diípọ Fágúnwà ÌWÚRE Ìwúre Kẹwàá Abẹ́rẹ́ kan kìí kọ ohùn aṣọ Kọ̀ọ̀nkọ̀ kan kìí kọ ohun odò Òkú aláǹtakùn kì í bónílé wíjọ́ Òkú alákàn kan kì í wàràn . Ikú ọmọ ní í pá yindin yindin Bẹ́ẹ̀ sì nikú màjèsín ni í payítalẹ̀ . Báfẹ́fẹ́́ bá fẹ́ Gbogbo ìtàkùn á dọ̀bálẹ̀ Bíjì bá ń jà gbìjìgbìjì Gbogbo ìtàkùn á dọ̀bálẹ̀ . Ẹ̀fún kan kìí mọ́jọ́ Ojoojúmọ́ lọjọ́ ó yọ Bẹ́ẹ̀ sì lèèdì kan kìí móòrún Lásìkò lásìkò lòòrùn ún là . Kí aráyé má rí mi gbé ṣe Nípa Ọ̀rọ̀ Yorùbá Ọ̀rọ̀ Yorùbá A dá ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀ láti polongo èdè Yorùbá ní gbogbo ọ̀nà tí a lè gbà mú u wuyì fún tolórí- tẹlẹ́mù. Ipa tí a fẹ́ kó nínú ẹgbẹ́ yìí rọ̀ mọ́ gbígbé èdè Yorùbá lárugẹ, kí ó ma bàà di èdè tí kò ní ní alábòójútó ní ọjọ́ iwájú. Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé wón ti ka èdè Yorùbá sí èdè tí kò ní sí lórílẹ̀ ayé mọ́ bí àwọn elédè gan-an ò ṣe káràmáásìkìí èdè wọn. Ìpèníjà ni èyí jẹ́ fún awa ògidì ọmọ Odùduwà tí èdè yìí jẹ lógún jùlọ. Èrèdí ọ̀rọ̀ rè é tí a fi jẹ ọmọ ẹgbẹ́ yìí. Nínú ẹgbẹ́ yìí, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n, ọ̀mọ̀wé, àwọn olùkọ́ àgbà àti olólùfẹ́ Yorùbá ní ó wà níbí. A sì tún fi àǹfààní sílẹ̀ láti mọ ara wa ju báyìí lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ohun kan tí yóò ṣàǹfààní fún ẹgbẹ́ tí yòò sì mú ìmọ̀ kún ìmọ̀, kí ó má ṣe jáfara láti fi tó wa l'étí. Ire lójú owó ń rí, ire la ó máa rí o. Àṣẹ . ÒWE ÒWE: A kó bá ni l’Èkúté ilé, Ejò kìí j’àgbàdo . ÌTUMỌ̀: Ìṣẹlẹ̀ kìí dédé wáyé, ohun kan ló máa ń fà á wá . ÌTÀN: Ò tó ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn báyìí ní ìletò kan tí ń jẹ́ Sọkúlú lẹ bàá ìlú kan tí ń jẹ́ Fẹ̀yìntì. Ní gbogbo ìletò náà, kò sí alápatà kan (ẹlẹ́ran ní ń jẹ́ alápatà) ọkùnrin ẹlẹ́ran kan ní ń máa kiri wá sí ìletò náà. Ibi tóun pàápàá ń gbé jìnnà réré sí ìletò tó ń kiri wá. Ọjọ́ mẹ́tamẹ́ta ni ó máa ń kiri wá, torí èyí , gbogbo èèyàn ìletò náà ti mọ̀ ọ́n. Kódà, ní kété tó bá ti dé ni gbogbo èèyàn yóò ti mọ̀ torí gbogbo ọmọ kékeré inú ìletò náà ni yóò tẹ̀le e tí wọn yóò máa ba gbé ìpolówó ọjà rẹ̀. Tí bàbá ẹlẹ́ran bá ní “Yè-è-é, ó wọjú o, ẹ-ẹ̀rẹran, K-ẹ́-ẹ-sẹ́lẹ́ńkẹ́jọ̀”. Gbogbo àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tó tẹ̀ɔẹ yóò dáhùn . “Yè-è-é”, Igbe yìí ló ma ń polówo ọjà bàbá fún raa rẹ̀! . Ní gbogbo ìgbà tí bàbá bá gbé ẹran ka orí, ewé díẹ̀ , ni ó ma fi bò ó, yóò wá fi ọ̀bẹ ìgéran rẹ̀ lé e. À ṣé àwọn ẹyẹàwodi kan wà̀ ní ìletò yìí tí wọ́n ti máa ń ṣọ́ bàbá ní ìgbà tí ó bá ń kiri ká inú ìletò náà. Àwọn ẹyẹ àwodì ti ṣe ìpàdé ní àìmoye ìgbà láti kó gbogbo ẹran orí bàbá alápatà yìí ní ìgbàkigbà tí àwọn bá péjú, torí ọ̀pọ̀ ìgbà ní bàbá sì ń kiri wọ inú ìletò tí àwọn àwodì yóò sì ti wá nǹkan jíjẹ, mímu wọn lọ. . À mọ́ lọ́jọ́ tí ìṣẹlẹ̀ yí máa wáyé, bàbá kiri ẹran wọ inú ìletò, àwọn ọmọdétẹ̀lé bàbá ẹlẹ́ran bí ìṣe wọn. Bàbá ń ta ẹran káàkiri, ó dé ọ̀dọ oníbáráà kan, ó sọ̀kalẹ̀, òun àti onítọ̀ún dúǹá dúrà ẹran dáadáa. Ìná sì wọ̀, bàbá gé ẹran fún onítọ̀ún ló bá tún gbé ẹrù rẹ̀ lórí ló ń kiri lọ. À ṣé àwòdì méjì ti rí bàbá láti ìgbà tó ti wọ inú ìletò. . Ǹ jẹ́ bí bàbá ṣe gbé ẹran nílẹ̀ tó gbé e lérí ní àwọn àwòdì méjì fò bàràbàrà tí wọ́n ya lu inú ọpọ́n ẹran bàbá. Yé è! Ni bàbá fi igbe ta, àwọn àwòdì kò rí ẹran gbe, ọ̀bẹ bàbá ni wọ́n kì mọ́lẹ̀. . ÒWE Ẹni sọ̀rọ̀ púpọ̀, á ṣìsọ . Translation: One who talks much is likely to make mistakes . Lílò: Ìkìlọ̀ pé ó dára kí a yára gbọ́ ṣùgbọ́n kí a lọ́ra láti fèsì; nínú ísọ̀rọ̀ púpọ̀ ju bí ó ti yẹ ni a lè ká ọ̀rọ̀ mọ ‘ni lẹ́nu. ÌṢERÉ ÌTÀKÙRỌ̀SỌ LÁÀRÍN- ÍN ÈMI ÀTI ÌYÁ ONÍWÓRÓBO Ayọ̀ọlá: Ẹ káalẹ́ o Ìyá Alájé: Ooo . Ayọ̀ọlá: Kínni ẹ ni ní títà tí mo lè fi mu gàrí Ìyá Alájé: Ẹ̀wà ló wà . Ayọ̀ọlá: Lẹ́yìn ẹ̀wà, kínni ẹ tún ní Ìyá Alájé: Kòsí . Ayọ̀ọlá: Ó da, ṣé ẹní bàbá dúdú Ìyá Alájé: Kòsí . Ayọ̀ọlá: Tí ó bá jẹ́ bẹ̀, ẹ ta ẹ̀wà múrí kan àbọ̀ wá Ìyá Alájé: Ṣé ìyẹn kìí ṣe ‘sixty nairà’ bí . Ayọ̀ọlá: Rárá o, ‘thirty nairà’ ni mo sọ; múrí kan jẹ́ ‘twenty nairà, àbọ̀ rẹ̀ jẹ ‘ten nairà’, tí a bá ṣí i pọ̀ yóò fún wa ní , ‘thirty nairà’ , múrí mẹ́ta á sì jẹ ‘sixty naira’. Ṣé ó yé? Ìyá Alájé: Bẹ́ẹ̀ni, ó yé, ẹ ṣeun gan- an fún àlàyé yín . Ayọ̀ọlá: Ọlọ́hun ló ni í Ìyá Alájé: Ṣùgbọ́ ṣá o, kòsí ẹ̀wà múrí kan àbọ̀. Ati ‘fifty nairà’ ni ẹ̀wà ti bẹ̀rẹ̀, ṣíbí kan sì ni . Ayọ̀ọlá: Á jẹ́ pé owó yín ti dé nì yẹn Ìyá Alájé: Àmín ooo . Ayọ̀ọlá: Ǹ jẹ́ ẹ ní ṣúgà Ìyá Alájé: O wá, èló lẹ fẹ́ . Ayọ̀ọlá: Ẹ mú oní múrí kan wá. Ǹ jẹ́ ẹ ní ẹ̀pà náà Ìyá Alájé: Bẹ́ẹ̀ni, ó wà . Ayọ̀ọlá: Tí ó bá jẹ́ bẹ̀, ẹ mú ẹ̀pà àti ṣúgà, múrí kàn-àn kàn wá (Bí mo ṣe gba ṣúgà àti ẹ̀pà lọ́wọ́ Ìyá Aláje rè é, tí mo sì fùn- un ni ogójì náìrà/ múrí méjì) Ọfọ̀ Ẹ̀yọ́nú Bépo bá ń lérí sọná Ijó ni iná fi i jó Bí àdí bá ń lérí sí òòrùn Ayọ̀ ni òòrùn fi ń yọ A kì í gba igbó lọ́wọ́ onígbó A kì í gba ọ̀dàn lọ́wọ́ ọlọ́dàn Ẹja ńlá ní í fòkun ṣelé Ọ̀nì gìdìgbà níí fọ̀ṣà sàrípọ̀nlọ Ẹ yọ́nú sí mi Kí wọ́n má lè ṣí mi nípò Kí wọn yọ́nú sí mí o ORIN Ẹskẹkẹnkẹ Àyìndé(2) Òdòlayé Àrẹ̀mú ... Yásàlámọ̀ Yásàlámọ̀ alaekum Ìgbòwó ló n mọ́lẹ̀, ọmọ Kòsọ́kọ́ Ẹ dákun, e má jẹ́ ki tẹ sẹ̀ ó gbọ̀n dànù Ẹ dákun, e má jẹ́ ki tilẹ̀ ó pọ̀jù ti tẹnu lọ Mi ò màmà ríhun tó pọ̀ tí ò ní tán Ìrí tí morí, ṣé mo rí atare, Ẹskẹkẹnkẹ À ní ọmọ Àmọ́dù, ọmọ Ẹjalónibú Apá ọ̀tún tí mo wò, mo tún rí kábá Báǹkí onímuṣin, ọ̀bùn muṣin Onímuṣin, ọ̀bùn muṣin Ọgbọngbọn bí ọjọ́ kanrí, agùntáṣọ́ọlò Orí mọ́námọ́ná ṣiyàn ládé Kò sí ìyà oró n Muṣin mọ́ páà Ẹnu igbà tó joyè yìí náà ni, ọba Muṣin Ìrí tí mo rí, ṣe mo rí atare? Apá ọ̀tún tí mo wò, mo tún rí kábá Ẹ̀yìn tí mo wò, mo rí àgádágodo Ẹskẹkẹnkẹ, Ẹskẹkẹnkẹ Ọ̀rọ yìí e débi à ń yọ orùka Ṣébi min ò lóògùn, kédì ewé jíjá Àyìndé bí mo bá dejò, ó sá di igi oko Èyí tí wọ́n ṣe tó kọ̀ tí kòjẹ́ oo; yéèèèè Àtèyí wọn máwọ̀ wèrè ṣe Ní Muṣin Olówó kan ò lè dún kowéè lé ọ lérí mọ́ Àyìndé ọwọ́ ti tẹ àgádágodo wọn Elégbodo kan ò lè dún kowéè lé ọ lérí mọ́ Àyìndé ọwọ́ ti tẹ àgádágodo wọn Akéwejẹ! Akéwejẹ!! Akéwejẹ gbogbo Èkó Kìnìún Ìdímù tíí ṣẹ́mọ à á ṣẹ́ mọ kọ́lá ó dígbọ́n N ò rí ohun tí kòlè fi tọrọ Íí ràlẹ̀ í fún èèyàn Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ mí oo Bí ebi bá ń pamí oo B’órun bá ń kùn mí oo Ó dilé Ẹskẹkẹnkẹ Kìí pé àlejò pé ibo lóti wá Ọmọ Ẹjalónibú Bí Géḿbérí bá wọlé ẹ, á jẹun Bí ó bá jẹun mumi tán, á ní kó máa lọ Ẹskẹkẹnkẹ Àjọsọ Kìnìún ọmọ Àdísátù Bí Géḿbérí bá wọlé ẹ, á jẹun Bí ó bá jẹun mumi tán, á ní kó máa lọ Ọ̀ríjínà Yoòbá Bí ó bá jẹun mumi tán, á ní kó máa lọ Ẹskẹkẹnkẹ Kìí pe wọ̀bìà, Bí ó pajá ẹ̀ kó wá jẹun Ṣùrù lọlá tí ń bọ́ báálé tẹrú tọmọ Baba toní o ó dà lo dàyìí Àjọsọ Séríkí Àgbà toní o ó dà lo dàyìí Bo ṣe bí o ṣe ń ṣe ni, ni o máa ṣe Àyìndé, Baba Akeem Bí o bá ti rí ọmọ kékeré o máa fọmọ kékeré mọ́ra Baba Enjiníà, baba lọ́yà, bàbá adájọ́ Àyìndé bí o rágbà o f’àgbà mọ́dọ ọọọọ Ẹskẹkẹnkẹ Baba dókítà Àgbà ló ń báni ṣèlú, ọmọ kékeré ni ń báni tún ilé ẹni ṣe Ẹskẹkẹnkẹ Àyìndé má j’obì lọ́gànjọ́ mọ́ ọọọ Ẹni bá rí ni tán ló ń ṣekú pani Kòrí kòsùn ló pa Jimoh, ọmọ Àgbókí l’ádífá Àpọ́nlé òògùn, là ń so ońdè mọ́wọ́ Ẹskẹkẹnkẹ Àyìndé Tani ikú ò bá faragbá tí kò mú lọ? Ìdájí ìdájí lo l’ógùn ń kú, ọmọ Àgbókí l’ádífá Ọ̀ré rẹ ńkọ́, ṣé ó ń bẹ lá làáfíà ara? Bùṣìrá, ọmọ Agúnbíadé Ikú gberí kangí ọmọ Agúnbíadé ÌWÚRE ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀ A kò ni bọ́jọ́ ọlọ́jọ́ lọ A kú ìbẹrẹ̀ ọ̀sẹ̀ yii A ò ní ṣe àṣetì nídǐ iṣẹ́ wa À tà jèrè ọjà Kí a má ríbi elénìní Kí òní sànwá sí rere ÀKANLÒ ÈDÈ ÀKANLÒ ÈDÈ APÁ KẸRIN 1. Àgùntàn bu(ni) jẹ. ṣe aìlè bá obìnrin lò pọ̀ 2. Ẹja ǹ bákàn. Ire tàbí ibi 3. Já(ni) sí agbami. Padà lẹ́yìn ẹni láàrín ín méjì 4. Igi lẹ́yìn ọgbà. Aláfẹ̀yìntì 5. Rí ọwọ́ họrí. Ní owó 6. Ṣé ní bòńkẹ́lẹ́. ṣé ní ìpámọ́/ kọ̀rọ̀ 7. Pín gààrí. Pínyà tàbí dẹ́kun àjọṣepọ̀ 8. Wá fìn-ín-ìn ìdí kókò. Ṣe òfintótó/ ṣe ìwádǐ láti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ 9. Nu (ni) lọ́rọ̀. Sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí ni 10. Mú ọ̀gẹ̀dẹ̀ nínú ọsọ́. Ya òmugọ̀ ÀRÒKỌ Ọ̀FỌ̀ ṢẸ̀ WÁ NÍNÚ ẸBÍ WA APÁ KẸRIN . Nǹkan púpọ̀ ni mó fẹ́ bèèrè lọ́jọ́ náà lọ́hǔn, ṣùgbọ́n n kò rí ẹni bi. Gbogbo èèyàn ló bara jẹ́ tí wọ́n ṣe bí ẹni pé wọn kò tilẹ̀ rí àwa ọmọdé- ilé. Títí kan àwọn tí wọ́n máa ń yọ̀ kí wa, lásán ni wọ́n kí wa. Obìnrin kan tilẹ̀ sọkún tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí kò tilẹ̀ mọ̀ pé èmi ni mo jókǒ ní kọ̀rọ̀ kan ní ẹ̀yìnkùlé. . Wọ́n ti gbé ìbùsùn bàbá mi sí pálọ̀. Mo rí gbogbo àwọn nǹkan tí wọ́n ti rà láti fi sin òkú náà kí wọ́n tó sin ín. Ńṣe ni mo fi gbogbo rẹ̀ ṣe ìran wò. Wọ́n ní kí gbogbo ènìyàn yẹra o, wọ́n ń gbé òkú bọ̀. Mo gbọ́, mo sì fẹ́ wò ó, ṣùgbọ́n ìyá wa àgbà kan lé mi sẹ́hìn. Ó ní, ‘Àwọn ọmọ ayé ìdayìí mà láyà o. Wọ́n ní wọ́n ń gbé òkú bọ̀, ìwọ Ìyábọ̀ ń yọjú. O fẹ́ wo òkú ni?’ Bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ kí n rí òkú náà wò bí wọ́n ṣe ń gbé e bọ̀. Yàrá bàbá mi ni wọ́n gbé e lọ. Mo sì mọ̀ pé wíwẹ̀ ni wọ́n lọ wẹ̀ ẹ́ nítorí mo ri àwọn ènìyàn wa tí wọ́n ń gbé kàn-ìn-kàn-ìn, igbá omi, aṣọ ìnura, wọ ilé. Ó pẹ́ kí wọ́n tó jáde, wọ́n ní wọ́n ti wẹ òkú tán, wọ́n sì ti wọ ‘ṣọ fún un tán. Wọ́n ní wọ́n ma gbé e lọ sí pálọ̀. Wọ́n wá tẹ́ ẹ sí orí ìbùsùn bàbá mi tí wọ́n ti tẹ́ aṣọ funfun lé. . Ó tó agogo méjìlá ọ̀sán báyìí. Tí kò bá sí ọ̀fọ̀ tí ó ṣẹ̀ wá ni, irú àsìkò báyìí , ilé- ìwé ni èmi, ẹ̀gbọ́n àtí àbúrò mi ìbá wà ṣùgbọ́n wọn kò jẹ́ kí á lọ sí ilé- ìwé. Nǹkan púpọ̀ ni ó jẹ́ nǹkan ìyàlẹnu fún mi l’ọ́jọ́ ìsìnkú yìí. Wọ́n ní kí emi àti ẹ̀gbọ́n mi wọ aṣọ funfun kan tí a máa ń wọ̀ lọ sí ilé- ìsìn. Ìyá mi sì fún wa ní gèlè dúdú láti wé. N ò wé gèlè dúdú rí ṣùgbọ́n a ṣe bí wọn ṣe wí. A jókǒ sí ẹ̀hìnkùlé, a n gbọ́ ìkini òkú àti ìdánilóhùn oríṣiríṣi. Ẹlòmíràn á sọkún kíkorò, á sì kí àwọn ènìyàn wa báyìí pé: Ẹ pẹ̀lẹ́ o. Ẹ kú àjálù. Ẹ kú ọ̀fọ̀. Ọlọ́run yóò ṣe é mọ bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run kò ní í jẹ́ k’a r’írú rẹ̀ mọ́. . Ẹlòmíràn á tún dé, a ní ṣe irú rẹ̀ ní tiyín mọ́. Ọlọ́run yóò fi mọ bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run á tìkùn ìbànújẹ́. . Síbẹ̀ ẹlòmíràn tún lè kí wa pé: Ẹ pẹ̀lẹ́ o. Ẹ kú ẹjọ́ tí Ọlọ́run dá yín. Ọlọ́run kò ní í fi irú bẹ́ẹ̀ sí sàkání yín mọ́. Ọlọ́run kò ní í jẹ́ kí ẹ kú àkúrun mọ́ o. . Ìdáhùn àwọn òbí wa sí kíkí ọ̀kan-ò- jọ̀kan wọ̀nyí ni: Ẹ ṣeun, ṣeun. Ẹ ṣeun, a dúpẹ́ o. Ọlọ́run kò ní í ṣe é ní àáró o. Ọlọ́run kò ní í jẹ́ kí ẹ fi irú rẹ̀ gbà á o. Bí a ti rí náà nìyẹn o. . - ÌYÁBỌ̀ ÀṢÀ ÌSỌMỌLÓRUKỌ APÁ KEJÌ: ÈTÒ ÌSỌMỌLÓRÚKỌ Kí ó tó di ọjọ́ ìsọmọlórúkọ, oríṣiríṣi orúkọ ni a máa ń pe ọmọ titun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Àwọn mìíràn a máa pè é ní àlejò nítorí pé wọ́n kà á sí àlejò tó wá bá ni; ṣùgbọ́n wọn kò kà á sí àlejò tí yóò tún padà, bí kò ṣe èyí tí yóò máa bá ni gbé lọ títí. Àwọn mìíràn a máa pè é ní ìkókó, túnfúlù tàbí aròbó. Àwọn ẹ̀yàYorùba mìíràn ní orúkọ tí wọ́n ń pe ọmọ titun tí kò tíì ní orúkọ ní ẹ̀ka- èdè ti wọn. . Ní ìbẹrẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ọjọ́ mẹ́fà ni à ń sọ ọmọ lórúkọ ìbáà jẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin. Ṣùgbọ́n àwọn ìran tàbí ìdílé pàtàkì pàtàkì pàápàá ní ààrin ẹ̀yà Yorùbá Ọ̀yọ́ ní ètò ìsọmọlórúkọ tó yàtọ̀ sí ọjọ́ mẹ́fà. Ní ìdílé Olú- òjé, Onígbẹ̀ẹ́tì, Olókùn- Ẹṣin, Arẹ̀sà, Oníkòyí àti Olúgbọ́n, ọjọ́ keje ni à ń sọ ọmọbìnrin lórúkọ. Ọjọ́ kẹsàn án ni ti ọkùnrin. Bí a bá bí ìbejì ní ìdílé wọ̀nyìí, tí àwọn méjéèjì sì jẹ́ obìnrin, ọjọ́ keje la ó sọ wọ́n lórúkọ. Ṣùgbọ́n tí àwọn méjéèjì bá jẹ́ ọkùnrin, ọjọ́ mẹ́sàn án ni a ó sọ wọ́n lórúkọ. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjéèjì bá jẹ́ ọkùnrin tí èkejì sì jẹ́ obìnrin, ọjọ́ kẹjọ ni a ó sọ wọ́n lórúkọ ní ìdílé náà. . Ọjọ́ ìsọmọlórúkọ ní ìdílé Ọlọ́fà tún yàtọ̀. Ní ìdílé Ọlọ́fà, ọjọ́ méje ni à ń sọ ọmọkùnrin lọ́rúkọ. Ọjọ́ karùn ún ni ti obìnrin. Ọjọ́ kẹfà ni ti àwọn ìbejì tí ọ̀kan jẹ́ ọkùnrin tí èkejì jẹ́ obìnrin. Ṣùgbọ́n tí àwọn ìbejì náà bá jẹ́ ọkùnrin, ọjọ́ keje la ó sọ wọ́n lórúkọ. Bí wọ́n bá jẹ́ obìnrin, ọjọ́ karùn ún ni. Ní ìdílé Aláàfin, ọjọ́ kẹfà ni à ń sọ ọmọ lórúkọ. . Láyé òde òní, ìyípadà ti dé bá ọjọ́ ìsọmọlórúkọ. Kí gbogbo rẹ̀ lè dọ́gba, ọjọ́ kẹjọ ni à ń sọ ọmọ lórúkọ ní ibi púpọ̀ ilẹ̀ Yorùbá. Ìdílé kọ̀ọ̀kan ló ní orò- ilé tí obìnrin tó bí ọmọ gbọ́dọ̀ ṣe láti ọjọ́ tí ó bá ti bímọ títí di ọjọ́ ìsọmọlórúkọ. Orò kan wọ́pọ̀ ní ibi púpọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá. Èyí ni ‘kíkó- ọmọ- jáde’ ní ọjọ́ ìsọmọlórúkọ. . Inú ìyàrá ni ìyá ìkókó gbọ́dọ̀ wà pẹ̀lú ìkókó náà láti ọjọ́ tí ó bá ti bímọ títí di ọjọ́ ìkomọjáde.Ibẹ̀ ni wọn yóò maá dàná fún un yá. Ìgbà tó bá fẹ́ yàgbẹ́, ìgbà tó bá fẹ́ tọ̀ tàbí ìgbà tí ó bá fẹ́ mọ́ra ni yóò maá jáde sí gbangba. Ọjọ́ ìsọmọlórúkọ ni a ó tó gbé ọmọ náà jáde láti inu ìyàrá bí ó bá jẹ́ ọ̀kan. Bí ó bá jẹ́ ìbejì, ọjọ́ náà la ó tó kó wọn sí gbangba òde. Ìdí nìyǐ tí a fi ń pe ọjọ́ ìsọmọlórúkọ ní ọjọ́ ìkómọjáde. . Ní ọjọ́ ìkomọjáde, àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ yóò péjọ síwájú ilé níbi tí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò máa ń dà sílẹ̀ láti orí òrùlé. Wọn yóò gbẹ́ ihò kéékèèkéé méjì síwájú ilé náà. Ìyá ��kókó náà yóò wọṣọ tó dára nítorí ọjọ́ ayọ̀ ni ọjọ́ náà fún un. Nígbà tí ìyá ìyá ìkókó báti jókòó níwájú ilé tán, àgbà obìnrin kan yóò wọlé lọ gbé ọmọ náà jáde láti inú ìyàrá. Ìyá rẹ̀ yóò gbà á. Wọn yóò máa da omi tútù sórí òrùlé bí ìyá ìkókó ṣe ń gbé omọ rẹ̀ bọ̀. Ẹ̀kán omi tútù yóò kán sára ìkókó. Ọmọ náà yóò ké nítorí omi náà ṣàjejì lára rẹ̀. Inú àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ tó péjọ yóò dùn fún igbe ayọ̀ tí ọmọ náà ké. Igbe náà sì tún fi hàn pé ara ọmọ náà dápé. Nígbà mìíràn, ẹ̀ẹ̀méje ni wọn yóò fi ara ọmọ náà gbe ẹ̀kán omi náà bí wọn ti ń gbé e wọlé, tí wọ́n ń gbé e jáde, bí ó bá jẹ́ obìnrin. Bí ó bá jẹ́ ọkùnrin, ẹ̀ẹ̀mẹsàn án ni. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ ìbejì, ẹ̀ẹ̀mẹ́jọ ni. . Bí a bá yẹ àṣà yìí wò, ó fi ara jọ ìṣamì àwọn ẹlẹ́sìn Krístì. Ó sì tún jẹ́ pé àwọn baba- ńlá wa ní ìmọ̀ ẹ̀sìn Krístì kí wọ́n tó wá tẹ̀dó sí Ilẹ̀- Ifẹ̀. Ṣùgbọ́n ṣáá, ìdí tí a fi ń ṣe àṣà yìí ni láti jẹ́ kí ara ìkókó náà mọ omi tútù nítorí ìgbà tí ìyá rẹ̀ yóò máa gbé e kiri. Láti ọjọ́ ìkómọjáde náà ni ìyá rẹ̀ yóò ti máa gbé e káàkiri bí ó bá ti fẹ́. - Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá Titun ORÚKỌ ORÚKỌ TÍ Ó JẸ MỌ ÀSÌKÒ 1. Ọ̀tẹ́gbẹ̀yẹ: Ọmọ tí a bí lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ ìlú. Ọ̀tẹ̀ náà sì ti gba ẹ̀yẹ ìdílé 2. Ogúnpọlá: Ọmọ tí a bí lẹ́yìn tàbí lásìkò ogun. Ogun ti pa ọlá ìdílé 3. Abíóyè: Ọmọ tí a bí lásìkò tí bàbá rẹ̀ wà lórí oyè 4. Abíọ́lá: Ọmọ tí a bí sínú ọlá tàbí lásìkò tí àwọn òbí rẹ̀ ní ọlá púpọ̀ 5. Abíọ́nà: Ọmọ tí a bí lásìkò tí ìyá rẹ̀ wà lójú ọ̀nà sí ibì kan yálà ọ̀nà oko, ọ̀nà odò, ọ̀nà ọjà, ìrìn- àjò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ 6. Abíọ́sẹ̀/ Abọ́sẹ̀dé/Ajọ́ṣẹ̀/ Jọ́ọ̀ṣẹ̀ (Ọjọ́- ọ̀sẹ̀): Ọmọ tí a bí lọ́jọ́ ọ̀sẹ̀ Òrìṣà-ńlá; tàbí lọ́jọ́ ọ̀sẹ̀ òyìnbó lóde òní. 8. Bọ́sẹ̀dé: Orúkọ obìnrin ni èyí 9. Abíọ́dún/ Abọ́dúnrín/ Abọ́dúndé: Ọmọ tí a bí lásìkò ọdún pàtàkì kan- Ó le ṣe ọdún ẹ̀sìn tàbí ọdún ìlú 10. Ọdúnjọ/ Ọdún- Ifá/ Ọdúnayọ̀: Ọmọkùnrin tí a bí lásìkò ọdún Ifá tàbí ọdún mìíràn 11. Babájídé/ Babátúndé/ Babárìndé/ Babáwándé: Ọmọkùnrin tí a bí ní kété tí bàbá rẹ̀ kú. Orúkọ yìí fi ìgbàgbọ́ Yorùbá nínú àjínde múlẹ̀ 12. Yéwándé/ Yéjídé/ Yétúndé/ Ìyábọ̀dé/ Yésìdé: Ọmọbìnrin tí a bí ní kété tí ìyá bàbá rẹ̀ kú 13. Babárínsá/ Babárímisá/ Òkúgbésàbí: Ọmọ tí a bí lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀, bí ọmọ bẹ́ẹ̀ bá jẹ́ ọkùnrin 14. Jọ́họ̀jọ́/ Yérímisá: Ọmọbìnrin tí a bí tí ìyá rẹ̀ sì kú lọ́jọ́ náà tàbí kí á tó sọ ọ́ lórúkọ 15. Adéọjọ: Ọmọkùnrin tí a bí tí ìyá rẹ̀ sì kú lọ́jọ́ náà tàbí kí a tó sọ ọ́ lórúkọ 16. Àbíìbá: Ọmọ tí a bí lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, pàápàá bí ó bá pẹ́ díẹ̀ tí baba rẹ̀ ti kú kí a tó bi i 17. Ábíára: Ọmọ tí oyún rẹ̀ kò tí i hàn dáadá tí baba rẹ fi kú. Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ ju oṣù mẹ́sàn- án lọ tí baba rẹ̀ ki á tó bí i 18. Babáyẹjú: Ọmọbìnrin tí a bí lẹ́yìn ikú baba rẹ ORIN ESKEKẸNKẸ ÀYÌNDÉ(1) - Odòlayé Àrẹ̀mú AwúsùbìLáàyì Mínàṣàìtọ́nì Rọ̀jíími Bísímìláàyi Aramọ́ọ́ni Rọhíìmì . Àti wálé ayé ọjọ́ Ìbà lọ́wọ́ rẹ Odòlayé ni ń wí ìbà yìí o . Àti wọ̀ oòrùn Ìbà lọ́wọ́ rẹ . Àáfà tó yàn, tó yan jú Tínú ẹ̀ mọ́, tó ya wòólì Ìbà lọ́wọ́ ẹ̀yin o . Ẹ̀yin tẹ́ ẹ layé Ìbà lọ́wọ́ ẹ̀yin o . Ẹ̀yin ọmọ kéèkèèké tẹ́ ẹ ṣẹ̀ lẹ́yìn wa Ìbà lọ́wọ́ ẹ̀yin o . Kini ‘ǹfààní ẹni tóní ọwọ́ ayé ò le tẹ òun Tí ń janu, tí ń ṣagbaja, tí ń tún minu Àkámarà èé jẹ́bẹ̀ . Ìgbà tí ayé bá ṣe èèyán tán Wọn á sì dárò bọnu Tí ayé bá ṣe èèyán tán, wọn a l’ódò rè é gbétí lé . Ṣé kí n máa lọ, ṣé kòsí nǹkan? Ègbè: Wọ́n ní kòsí ǹkankan . Mo ríbà ‘i’ ríbá, mo ríbà dagbaro Ẹbọra lágbó ẹgẹ, Ọ̀bá di méji; a gbẹwọ̀n gbẹ̀gẹ̀dẹ̀ . Pẹ̀lẹ́ bí ẹ gbóhùn àríri, abínú fọhùn bí ènìyàn Mo ríbà ‘i’ ríbá, mo ríbà ìyá mi oo Ajíbọ́lá ẹdan ��yá mi ẹdọ̀ ọrọ oo Ọ̀rọ̀ tí ń gbénú ilédì tí ń kùn yùnmùyùnmù . Ní alẹ́ yìí, ìbà lọ́wọ́ Ajíbọ́lá Ará ìlú ète, ará ilú eédú . Ọlọ́ṣùn ún tẹ́rẹ́, abirù tínrín Bóbá dú lójú, a dú lénu Aájò lápá ìsàlẹ̀ woyìwoyì Afínjú Àdàbà tí ń jẹ́ láàrín ín òrófo Afinjú ẹyẹ tí ń jẹ ní gbangban ilé ọba . Àákú ayé ò bá o Aa Àákú ayé ò bá o, ilẹ̀ ló tún tẹ̀yin ṣe Ọmọ aláya ọba, èyí tí ń ṣàǹfàni nínú ilédì, ọmọ àgbàgbà ìmùlẹ̀ Afínjú ońmùlẹ̀ tí ń so kùtúkùtú mọ́wọ́ . Ẹ má wò ó óóó Ẹ̀yin ọ̀dàlè ènìyàn Ṣòkè ṣodò Ẹlẹ́nu mẹ́rin-dín-lógún Agbọ́ yìí sọ̀ yìí; Asọ̀lú kọ̀lú Kẹ́ni mánǐ; Wèrè; Dìgbòlugi . Ẹ má debi a ò pèyín o Ẹ ò gbọdọ̀ wo o, ojú ò gbọdọ̀ ri . Ẹ ò wá wo ọmọ inú ọgbà bí wọ́n ti ń ṣe Àwọn ọmọ Àbẹ̀ní, ọmọ Oótù Ifẹ̀ . Ní alẹ́ yìí, ìbà lọ́wọ́ Dángbọ́ngbọ́n baba kóko Erù ọgbọ̀n gandàn, baba Ìlosùn . Aṣọ mẹ́rin-dín-lógún laṣọ Ṣọ̀npọ̀nná Ọ̀kan lahún Ìlárá- Eskẹkẹnkẹ Hájì kámaṣọ Yínmíyínmí píṅkin Ọgọgọlúmọlúmọ Apẹran máwàkú, olókìkí òru . Ìbà lọ́wọ́ yín, atìdí mùjẹ̀ èèyàn Ìyá mi, ọ̀rẹ́rẹ́ oo, ooooo, ooooo Ati ojú j’orí oo Ati ẹdọ̀ jọkàn Ati òróǹró jẹ̀fun Ọ̀gàlàǹta Ajẹran òró òó Ajẹ ẹ̀dọ̀ èèyàn mabì Ẹ̀yin lẹ kọ́mi lódù, tẹ sìnmí wálé ayé Tẹ́ẹ sọ pé ilé ayé tí mo wá, orin ni kí n máa kọ, kí n máa fi jẹun . Èkó náà la wàyìí Olú Nàíjíríà gan la wàyìí Muṣin la wàyìí Ọ̀dọ Ẹskẹkẹnkẹ la wàyìí Ọ̀dọ ọmọ Ààmádù la wàyìí Ọ̀dọ̀ Àyìndé la wàyìí Ọ̀dọ Kìnìún Ojúwóyè la wàyìí Ọ̀dọ Ìyàndá ọmọ Àdísátù la wàyìí Ọ̀dọ Akódúdú la wàyìí Ẹ dákun, ẹ má jẹ̀ kí tọwọ́ ó bọ́ TALO MỌ ỌN? ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÓ TA KÓKÓ 1. Kíni 'Òkú ewúrẹ́ tí í fọhùn bí ènìyàn' 2. Kíni Yorùbá ṣe ń kí èèyàn báyìí: 'Ẹ kú arógun' 3. Ibo ni 'Ìgẹ̀' wà ní ààgọ̀ ara? 4. Tani olórí 'Ẹgbẹ́ Onímọ̀ Èdè Yorùbá?' 5. Tani Yorùbá máa ń kí báyìí 'Ẹ rìn wá'? ORÍKÌ ÌKAMÒDÙ Ìkamòdù dúdúmọ̀ọ́dú, ẹlẹ́wìrì ihò. Ó kọjá nínú igbó, òórùn gba ‘gbó kankan; Ó kọjá l’ókè ọ̀dàn, òórùn gba ‘jù. A-jí-kó-òórùn- hárí a b̂ara dúdú kunkun. . Ìkamọ̀dù kì í lọ s’ógun àìm’ẹ́rú- bọ̀- wálé. Èyí t’ó lọ s’ógun tí kò m’ẹ́rú wálé Di à- níkàn- dá- jẹ̀ láàrin ìgbẹ́, kò tún sun inú ihò mọ́; Ó di k’ó máa sun abẹ́ ewé, abẹ́ igi kiri. . Ṣé Ìkamọ̀dù l’ó jagun l’ọ́jọ́ kan, ọ́jọ́ kan, L’ọ́jọ́ tí wọ́n fẹ́ ṣoró n’íhò ọ̀run. Ìkamọ̀dù l’ó lọ s’ógun ibá ikán jà, Bí wọn ti ń pa ikán n’ikán ń pa wọ́n. Ọ̀rọ̀ kò wọ̀ mọ́ Ìkamọ̀dù dá òórùn sílẹ̀ l’álẹ́ ihò, Níbi tí gbogbo ikán ti ń lé ‘mú òórùn bébé. Fún òórùn t’ó gba ‘nú ihò, t’ó sì gba ‘gbo kankan, Àwọn Ìkamọ̀dù gb’ọ́fá fùrọ̀. . Wọ́n n ta ikán ní mèlemèle. Ìkamọ̀dù jagun náà, wọ́n sì m’ẹ́rú wálé. Ni wọ́n fi n ki gbogbo àwọn Ìkamọ̀dù pé: Ọmọ a- fi- òórùn- jagun- m’ẹ́rú- kere; Wàrànwéré l’ogun Ìkamọ̀dù. ÀRÒKỌ Ọ̀FỌ̀ ṢẸ̀ WÁ NÍNÚ ẸBÍ WA APÁ KẸTA . Wọn kò tilẹ̀ lé àwa ọmọdé sí ẹ̀hìnkùlé. Wọ́n ní kí gbogbo ilé kúnlẹ̀ kí á gbàdúrà. Nínú ọ̀rọ̀ àdúrà yìí ni mo fi ọgbọ́n gbe pé àbúrò bàbá wa ti kú. Kí àlùfáà tó gbàdúrà tán, kí àlụ̀fáà kejì tó bẹ̀rẹ̀ Oore Ọ̀fẹ́, ni ẹkún àti ariwo ti gba ilé kan. N ò tilẹ̀ le sọ bí mo ti ṣe kúrò ní pálọ̀ wa ní ọjọ́ náà. Mo lọ sí yàrá èmi àti ẹ̀gbọ́n mi. Mo sọkún, inú mi sì bàjẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó ní láti jẹ́ pé ẹkún ni mo sun lọ sùn. . Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, kòì tíì tó aago márǔn ni ẹkún ìyá wa kan jí mi. Ó ń ki àbúrò bàá mi yìí ní oríkì ìran wọn ní mẹ́sǎn mẹ́wǎ. Mo gbọ́ tí ó ń sọ pé, ‘Ọmọ Òrónnà, Ọmọ Ìyáàlà, Ọmọ kí á fi ọ̀pá wá, k’á fi òjé, kí á fi ògèdègédé ọwọ wa dé Sẹri mọ́lẹ̀… Hee Hee Hee.’ Tí ó bá yá, á tún kì í lọ bí ilẹ̀ bí ẹní, á tún bú sí ẹkún. Kò sí ẹni tí ó lè sùn mọ́. ‘Ikú wo ni ó rí mi nílẹ̀, tí kò pamí, tí ó wá lọ pa ọmọ mi? Ọmọ mi tí kò ì ṣe ǹkan láyé’. Jésù gbàmí. Mo kú lónì o.’ Ẹ̀gbọ́n ìyá bàbá miobìnrin ni ó ń ké tí ó fa irun mọ́ ara rẹ̀ lórí, tí ó ń gbé ara rẹ̀ ṣánlẹ̀, tí ó ń sọkún kíkorò kíkorò bẹ́ẹ̀. Ǹkan ṣe! . Títí ilẹ̀ ọjọ́ fi ṣú, ariwo ẹkún ni ó gba ilé kan. Àti ìyá àti bàbá wa kò fi ẹnu kan óńjẹ. Aládǔgbò wa kan tí í ṣe ọ̀rẹ́ ìyá mi pàtàkì ni ó wá kó wa lọ sí ilé rẹ̀, tí ó fún wa ní àmàlà àti ewédú jẹ. Nígbà tí ó di alẹ́ tí ó mú wa padà wá sí ilé wa, a bá àwọn àlejò mélǒ kan tí wọ́n doríkodò. Ó dámi lójú pé wọ́n ti sọkún púpọ̀, agara sì ti dá wọn. . Ọjọ́ kejì ni ọjọ́ ìsìnkú. Ilé wa sì ni wọ́n ní wọn yóò tẹ́ òkú sí nítorí bàbá mi ni ó dúró bíi bàbá fún un, ilé onílé ni ó ń gbé. Ó kàn gba ìyàrá méjì l’ágbàsanwó oṣoòṣù ni. Mo rí I pé wọ́n ń palẹ̀mọ́ níilé wa, wọ́n kó gbogbo ǹkan ìtúnlé ṣe tí ó wà nínú pálọ̀ wa pamọ́ ní ilé wa pa mọ́. Gbogbo àwòrán ẹbi tí ó wà ara ògiri ni wọ́n da ojú wọn kọ ògiri. Agogo tí ó wà ní òkè tí gbogbo ènìyàn máa ń kọ́kọ́ rí nìkan ni wọn kò da ojú rẹ̀ bo ògiri. Ṣùgbọ́n wọ́n dá a dúró sí àsìkò tí olóògbè náà dákẹ́. Èyí jẹ́ agogo mẹ́rin ọ̀sán. Báyìí ni wọ́n sì fi agogo náà sílẹ̀ sí agogo mẹ́rin ọ̀sán fún ọ̀sẹ̀ kan gbáko, kí àwọn ènìyàn baà mọ àsìkò tí Bàbá Eréko fi ayé sílẹ̀ gan an. . - ÌYÁBỌ̀ ÒWE ÌTAN D’ÒWE Kò sí bọ́mọdé ṣe lè tètè jí kúrò nílé, oko ló má a bá kùkùté. . ÌTUNMỌ̀: Kò sí èèyàn ṣe lè ní òun gbọ́n tinú tẹ̀yìn tí kò níí bá ẹnìkan tó gbọ́n jù ú lọ níwájú. . ÌTÀN: . Àwọn bàbá wa bọ̀, wọ́n ní, ṣàṣà èèyàn ló ń fẹ́ni dékùn tá ò bá sí ńlé, àmọ́ tẹrú tọmọ ní ń fẹ́ni lójú ẹni. Ọ̀rẹ́ méjì kan wà láyé àtíjọ́; kòríkòsùn gbáá ni wọ́n. Iṣẹ́ òkòwò ni wọ́n jọ ń ṣe. Ọ̀rẹ́ kìn- ín- ní jẹ́ olóòótọ́ gidi, èkejì sì ń fi àṣírí rẹ̀ pamọ́ síkùn, kìí nà tán fọ́rẹ̀ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀rẹ́ yìí kò mọ̀. Ó wá gbàgbé pé ọba lókè Arínúríta, Olùmọ̀ràn ọkàn kọ ìwà mànáfìkí. Pẹ̀lú èyí ni àwọn ọ̀rẹ́ méjéèjì jọ ń ṣòwò, tí wọ́n ń bóde pàdé tí wọ́n sì ń kó èrè wọn pọ̀ sójú kan náà. . Ní ayé àtíjọ́, kò sí báńkì bíi tayé òde òni, bẹ́ẹ̀ ni àjọ tàbí èsúsú dídá kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́ pọ̀ rárá. Ihò ni àwọn èèyàn ń gbẹ́ tí wọn ma ń kówó pamọ́ sí lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fi ohun èlò tó nípọn bo ẹnu ihò náà, àwọn tó ní owó nìkan ló sì ń mọ́ èyí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ wí pé ìyàwó pẹ̀lú ọmọ kì í mọ ibi tí owó yìí fara sin sí. Ní bò míràn ẹ̀wẹ̀, wọ́n má á ń lo inú akèǹgbè láti kówó pamọ́ sí. . Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe lọ, àìsàn nawọ́ gán ọ̀kan nìnú àwọn ọ̀rẹ́ méjéèjí yìí, ikú foní kà sílẹ̀, ó mú onínúure lọ; ó wá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ tí inú rẹ̀ mọ́ sí ọ̀rẹ́ kejì ni àìsàn kì mọ́lẹ̀, inú àìsaṅ náà ló kú sí. Ní wàrànṣesà tí ọ̀rẹ́ yìí ṣán kú ni àwọn ará ilérẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ òpò ṣíṣe. Ẹni tí yóò gbẹ́ ilẹ̀, àwọn tí yóò wẹ òkú àti bàbá- ń- sìnkú. . (Bàbá-ń- sìnkúni ẹni tí ń darí gbogbo òpò àti wàhálà ìsìnkú ní ilẹ̀ Yorùbá.) . Ìròyìn dé sí etí ìgbọ́ ọ̀rẹ́ kejì pé ọlọ́jọ́ ti dé bá ọ̀rẹ́ tí wọ́n jọ ń ṣòwò. Lẹ́sẹ̀ kan ló dìde, tó gba ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ṣaláìsí lọ. Ó bá àwọn èèyàn lẹ́nu wàhálà ìpalèmọ́ òkú, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí sá síwá, sá sẹ́yìn; lẹ́yìn iṣẹ́ díẹ̀, ó tọrọ ààyè pé kí wọ́n jẹ́ kòun fẹsẹ̀ kan dé ọ̀dọ̀ oníbàráà wọn tó jẹ wọ́n lọ́wó, kí díẹ̀ ó tún lè gun orí owó tí wọn yóò ná ní bi ìsìnkú ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ẹ̀yin òǹkàwé, jagunlabí kò gba ibì kan lọ ju ibi tí òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó dolóògbé fi owó pamọ́ sí. . Dípò kí ó wu ìwà òòtọ́, kò ṣojú ṣẹ̀yìn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣe ni ó kó gbogbo owó tó wà níbi tí wọ́n ra sí(èyí ni ibi tí wọ́n kówó pamọ́ sí) tó sì dà á sápò, ló bá gbérà ló darí sí ilé ọ̀rẹ́ re tó dolóògbé níbi tó gbé dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tó ń ṣòwò lọ́wọ́. Kò pẹ́, kò jinnà, wọ́n parí gbogbo òpò òkú, wọ́n sì wé e láṣọ, ó di ibojì. Wọ́n dé ibojì, wọ́n ṣe gbogbo ètò tó jẹ́ ti ìsìnkú, àwọn ọmọ olóògbé kò gbàgbé ètò ìṣẹ̀mbáyé, wọ́n da yẹ̀pè sí ara òkú, bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí náà ni gbogbo èrò àti àwọn ìbátan òkú ń bá wọn da yẹ̀pẹ bo pósí. Ǹ jẹ́ bí ọ̀rẹ́ ẹni tó kú yìí ṣe bẹ̀rẹ̀ pé kí òun náà ó bá wọn da yẹ̀pẹ̀ sínú ibojì pẹ̀lú ẹkún èké lójú ni gbogbo owó tí òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ dà sínú ibojì òkú. Ó wá jẹ́ pé gbogbo owó tí òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó dolóògbé jọ ní nípàmọ́ kó tó kú tó lọ jí kó sápò ní ìrètí àti nìkan ná, ló dà sínú ibojì láì ku eépìnnì. . Ọ̀rẹ́ ọ̀dàlẹ̀ yìí kò mọ ohun tí yóò ṣe, inú ibojì ò ṣeé kó sí, kò sí ọgbọ́n tí owó le fì di ṣíṣà kúrò nínú ibojì, ọ̀rọ̀ wá dàbí ti akúwárápá tó gbé nǹkan adẹ́tẹ̀ sọnù ni, àìlọ́wọ́ kò jẹ́ kí wọn ó lè lura wọn pa! Pẹ̀lú ìbànújẹ́ àti oríṣiríṣi èrò ni ọ̀rẹ́ fi padà sí ilé. Ódá jókòó sínú ibojì ọ̀rẹ́ rẹ. Ọkàn rẹ̀ ń dá méjì, ó ń rò bóyá òkú ló mọ̀ọ́mọ̀ gba owó lọ́wọ́ òun, èrò m̀íràn sọ sí I lọ́kàn pé, kó lọ, ṣebí àṣìṣe lásán ni owó fi dà sínú kòtò. Ní gbẹ̀yìn, ọ̀ré gbé ìtìjú tà, ló bá sùn pé tí ó bá di kùtù hàì, òun yóò jí lọ́ sí ibi tí wọn sin ọ̀rẹ́ òun sí, pẹ̀lú èrò pé, òun nìkan yóò lè gbọ́n yẹ̀pẹ̀ inú ibojì jáde, owo àná yóò si di kíkó jáde. . Ní tòótọ́, ó jí dé ibi tí wọ́n sin ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí ó gbọ́n gbogbo yẹ̀pẹ̀ inú ibojì jáde, ó sì ṣa owó kúrò nínú ibojì. Ibi tí ó ti ń ṣa owó yìí ni ó ti gbọ́ gìrìgìrì ẹ̀sẹ̀, ó sá kúrò ní sàkàní ibojì ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó ṣáà ti ṣa owó dání tán, ṣùgbọ́n kò tíì gbọ́n yẹ̀pẹ̀ ibojì pàdà! Bí ọ̀dàlẹ̀ ṣe ki eré mọ́lẹ̀ tí ó ń sálọ, ǹ jẹ́ kí ó tó gbé ẹsẹ̀ kẹta ni, kùkùté(àgékù igi) kan bá kọ ní aṣọ, igi yìí kọ́ aṣọ ọ̀rẹ́ yìí dé bi pé tí èèyàn bá ríi, yóò rò pé ṣe ni wọ́n mọ̀ọ́ mọ̀ wé aṣọ náà mọ́ ara igi. . Ṣé bí èèyàn bá ṣe rere, ara kì yóò ti onítọ̀ún ní ìgbésẹ̀ kí gbésè yòó wù kó gbé láyé. Bí kùkùté igi ṣe lọ́ mọ́ ọ̀rẹ́, ló bu igbe ta pé “yéè, ẹ gbà-mí- o, òkú ti dì mí láṣọ mú o, ará igbó, èrò ọ̀nà, ẹ wá yọ mí nínú ọ̀fìn yí o”. Ipò yìí ni ọ̀rẹ́ ọ̀dàlẹ̀ yí wà títí tí ilẹ̀ fi mọ́ bá a tí àwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe háà, háà, háà, à ṣé bí ayé ṣe rí rè é! . Ìtìjú ojọ́ náà pọ̀ jù fun ọ̀rẹ́ búburú yìí kí ó tó mọ̀ pé kùkùté igi lásán ló lọ́ mó òun láṣọ, Ìtìjú yìí ló sì mú u kúrò ní ìlú náà. láti ọwọ́ ÀṢÀ ÌSỌMỌLÓRUKỌ APÁ KÌNNÍ ÍN: ÌGBÀGBỌ́ ÀWỌN YORÙBÁ NÍPA ORÚKỌ Àwọn Yorùba kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ètò ìsọmọlórúkọ nítorí pé a ka orúkọ sí ǹnkan pàtàkì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe àti àṣayàn ọ̀rọ̀ tí a máa ń lò ni ó fi bí orúkọ ti ṣe pàtàkì sí hàn. Fún àpẹẹrẹ bí a bá ní: ‘àpọ́nlé ni ìyá káà, kò sí ìyá kan ní káà tí kò ní orúkọ’, ohun tí a ń sọ ni pé kò sí ẹni tí kò ní orúkọ. Ẹni tí a bá fẹ́ pọ́nlé nìkan la lè dàpè tí a kò ní pẹ̀ é lórúkọ rẹ̀ pàtó. Ìṣòro púpọ̀ ni yóó wá bí ènìyàn kò bá ní orúkọ. A kò lè mọ bí máa pe ara ẹni tàbí bí a ó ti máa tọ́kasí ènìyàn kọ̀ọ̀kan bí ó bá jẹ́ pé a kò ní orúkọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nítorí náà, orúkọ wa la fi máa dá ara ẹni mọ̀. Bí ènìyàn bá jẹ́ méjì ni wọ́n le lo ‘ìwọ’ fún ara wọn tí ẹni a lò ó fún yóò fi mọ̀ pé òun ni à ń bá wí. Bí a bá lo ‘ìwọ’ láti tọ́ka sí ẹnìkan nínú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ẹni tí à ń báwí kò lè mọ ara rẹ̀ nítorí pé ‘ìwọ’ tọ́ka sí ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ni. . Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn Júù, Ẹlẹ́dàá tì kárarẹ̀ ló fún ẹ̀dá alààyè kìn-ín- ní ní orúkọ. Ẹ̀dá alàyè náà lósì fún ẹni tí a dá tẹ̀le e ní orúkọ. Òun náà ni Ẹlẹ́dàá fún láṣẹ láti fún àwọn ẹ̀dá mìíràn gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ, ewéko, ẹranko, igi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní orúkọ tí wọn yóò máa jẹ. Orúkọ tó fún wọn ni wọ́n sì ń jẹ́ di òní. Àṣẹ kan náà ni Ọlọ́run fún gbogbo ẹ̀dá láti fún àwọn ǹnkan wọ̀nyìí ní orúkọ ní èdè tí wọ́n ń sọ. Nítorí náà, orúkọ ṣe pàtàkì ni Ọlọ́run ṣe fún ẹ̀dá alààyè kìn- ín- ní ní orúkọ tí Ó sì fú un láṣẹ láti fún àwọn ẹ̀dá ìyókù ní orúkọ tí wọn yóò máa jẹ́. Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé o orúkọ á máa ro ènìyàn. Bí orúkọ ọmọ bá ti rí ni yóò ṣe máa huwà; nítorí náà ni wọ́ ṣe máa ń fara balẹ wo orúkọ tí wọn yóò sọ ọmọ. Yorùbá á tún máa pa òwe kan pé, ‘orúkọ ọmọ ni ìjánu ọmọ’. Ìgbàgbọ́ wa tí ó tún hàn nínú òwe yìí ni pé irú orúkọ tí á bá fún ọmọ kó ipa pàtàkì nítorí a kì í fẹ́ ba orúkọ ara ẹni tàbí ẹbí ẹni jẹ́ àfi àwọn ènìyàn lásán ni kì í bìkítà fún orúkọ rere wọn tàbí orúkọ ẹbí wọn. Nítorí ìfẹ́ àti fi orúkọ ẹni sí ipò iyì àti ẹ̀yẹ ni àwọn Yorùbá fi fi orúkọ wé ìjanu. Ọmọlúàbì yóò máa rántí àwọn ènìyàn rere tó ti jẹ́ orúkọ rẹ̀ síwájú, yóò sì máa gbìyànjú láti máa hùwà rere kí ó má baà ba orúkọ náà jẹ́. . Bí a bá ṣe àkíyèsí ìtàn ilẹ̀ Yorùbá lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, a ó rí i pé àwọn kan ti ba orúkọ wọn jẹ́ nípa ìwà búburú tí wọ́n ti hù. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló yí orúkọ wọn po nígbà tí orúkọ bẹ́ẹ̀ bá orúkọ àwọn ọlọ́ṣà, adigun- jalẹ̀ mu. Wọ́n yí orúkọ wọn po kí àwọn ènìyàn má baà máa rò pé ìbátan àwọn ọlọ́ṣà náà ni wọ́n. Nítorí náà, àwọn Yorùbá a máa dáàbò bo orúkọ rere wọn gẹ́gẹ́ bí wọn tí ń ṣọ́ra láti máa hùwà rere. Bí a bá rí ọmọ tó ń hùwà ìpáǹle nínú ẹbí, àwọn mọ̀lẹ́bí á máa kìlọ̀ fún un kí ó má ba orúkọ ẹbí wọn jẹ́. Ìwà rere, orúkọ rere ṣe pàtàkì fún àwọn Yorùbá nítorí náà ni wọ́n ṣe máa ń sọ pé orúkọ rere sàn ju wúrà àti fàdákà lọ. Dájúdájú wúrà àti fàdákà dára púpọ̀, wọ́n sì níye lórí gan- an. Ṣùgbọ́n bí orúkọ rere bá sàn jù wọ́n lọ, dájúdájú àwọn Yorùbá ka orúkọ rere sí nǹkan iyebíye tí a kò lè fi owó rà rárá. Ìgbàgbọ́ yìí ni ó ń mú wọn kó ara wọn níjàánu láti hùwà tí kò dára. Kíkó ara ẹni níjàánu láti tún orúkọ ẹni ṣe ló ń mú wọn máa pa á lówe pé ‘orúkọ ọmọ ni ìjánu ọmọ’. Bí a bá tún yẹ àwọn òwe àti àṣàyàn ọ̀rọ̀ mìíràn wò, a ó rí irú ìgbàgbọ́ yìí kan náà. - Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá Titun EWÌ AYÉ - Ayọ̀ọlá ọmọ Fádèyí Ayé ta’mọ tiye, yéèyéè Ẹnu aráye l’ẹbọ Ayé l’ópe adé ò gún Ayé l’ópe adé gún Ayé ṣoró ṣe èèyàn Ayé ọmọ Ayé Èèyàn ọmọ èèyàn Èèyàn abìdí yàn- án yà- án . Ẹnu aráyé, òrófó Imú aráyé, ajá Ikùn ayé, aláǹtakù Ìrù ayé, ọ̀bọ Èékánná ayé, ológbò Ayé ọmọ Ayé Èèyàn ọmọ èèyàn Èèyàn abìdí yàn- án yà- án . Èèyàn bí àparò l’ayé ń fẹ́ Ayé ò fẹ́ kí á ní Ayé ò fẹ́ kí á yó Ayé ò fẹ́ kí a tálákà Ayé ò tún fẹ́ kí a d’ọlọ́rọ̀ Ayé ọmọ Ayé Èèyàn ọmọ èèyàn Èèyàn abìdí yàn- án yà- án . Ẹnu ayé fi bú òriṣà L’ayé fi ń yin òriṣà Bí ó ṣe fẹ́rẹ́ fún òriṣà Ayé á fi ẹnu rẹ̀ tẹ́ńbẹ́lú òriṣà Òriṣà ni ò gbọdọ̀ bínú da igbá nù Ayé ọmọ Ayé Èèyàn ọmọ èèyàn Èèyàn abìdí yàn- án yà- án . Ayé á tijú olóṣì fún- un l’ẹ́kọ mu Ayé á bínú olówó gbèrò sọ́ ọ di tálákà Ayé ò fẹ́ á gbé ayé Ayé ò fẹ́ á kú fi ilé ayé sílẹ̀ Bákan méjì l’ayé Ayé ọmọ Ayé Èèyàn ọmọ èèyàn Èèyàn abìdí yàn- án yà- án . Méjì lẹnu ayé Ayé ẹlẹ́nu idà Idà olójú méjì Tibi tire la d’áyé L’ọmọ titun fí ń gbé ilé ọmọ rẹ̀ wáyé Ayé ọmọ Ayé Èèyàn ọmọ èèyàn Èèyàn abìdí yàn- án yà- án . Bí o wíire, ayé á ní o kò wíire Bí o wí i ní burúkú, ayé á ní o kò wí i ní burúkú Ayé á dẹ, dẹ̀dẹ́ ìti Ayé á lu, lùlú ìho Bí ayé bá dẹ, lúlu l’ayé ń lu Ayé ọmọ Ayé Èèyàn ọmọ èèyàn Èèyàn abìdí yàn- án yà- án . Bí ayé bá fẹ́ fún ni l’óúnjẹ Ayé á fi pàṣán ṣe óúnjẹ Láti fi dá ṣèríà fún elébi Má ṣe tọrọ lọ́wọ́ayé Ayé ò fún ni rí, kí á má fi òmíràn san Ayé ọmọ Ayé Èèyàn ọmọ èèyàn Èèyàn abìdí yàn- án yà- án . Ayé á pé o máa lọ Ayé á pé òun ń bẹ lẹ́yìn rẹ Bí o kò w’ẹ̀yìn wò Ayé ti já ẹ kulẹ̀ sẹ́yìn sẹ́yìn Tìfura tìfura lafi ń bá ayé rìn Ayé ọmọ Ayé Èèyàn ọmọ èèyàn Èèyàn abìdí yàn- án yà- án . Ayé ń bẹ Èèyàn wà Ta ni ayé, ta l’èèyan? Ayé l’èèyàn Èèyàn l’ayé Ayé ọmọ Ayé Èèyàn ọmọ èèyàn Èèyàn abìdí yàn- án yà- án . Ayé ò ṣé gbẹ́kẹ̀lé Èèyàn ò ṣé faratì Má ���e gbára lé ayé Òfúrúfú l’ayé Òfúùrù l’ayé Òfùùrù jágodo l’ayé Ayé ọmọ Ayé Èèyàn ọmọ èèyàn Èèyàn abìdí yàn- án yà- án IBI ABÚLÉ ỌJÀ ÀṢAMỌ̀ Ilú pọ̀ jàǹtirẹrẹ ní ìpínlẹ̀ Èkó bí o ti pọ̀ ní ìpínlẹ̀ mẹ́fà mìíràn tí ó parapọ̀ di Orílẹ̀ Ọmọlúàbí. Bẹ́ẹ̀ ìlú kìí wà kí ó mà ní olórí tàbí ibi tí ó ti ṣẹ̀ wa nígbà ìwáṣẹ̀, odò á ní orísun dandan. Ìlú tí a ó gbé yẹ̀wò lọ́sẹ̀ yìí ni Abúlé Ọjà. Ẹni bá ń lọ si Bàrígà, tí ó bá gba Yáàbá wọlé, yóò gba Abúlé Ọjà kọjá . Ẹni bá sì ń lọ si ilé Ẹ̀kọ́ fáfitì Èkó ti ìjọba àpapọ̀ kò lè yẹ Abúlé Ọjà sílẹ̀ láì má gbà á kọjá. Ìlú tí a ó gbé yẹ̀wò lọ́sẹ̀ yìí ni Abúlé Ọja. Ìlú Abúlé Ọjà kìí ṣe ìlú kékére rárá, gbogbo ohun tí ó ń tọ́ka sí ìlú ńlá lówà ní Abúlé Ọjà bí óti lẹ̀ jẹ́ pé Abúle tí ó wà nínu orúkọ yìí lè ṣi èèyàn lọ́nà láti rò pé Abúlé ni ìlú náà yóò jẹ́. Kò rí bẹ̀ rárá. Ṣùgbọ́n ẹni tí kò ì dé ibẹ̀ yóò rò pe Ìgbèríko ni. Abúlé Ọjà fẹ̀ dáadáa. Kò dín ní ọ̀dúnrún kìlómítà ló rọ kiriká ìlú yìí tí ẹsẹ̀ bá rìn ín ká. Fáfitì Èkó àti apákan Bàrígà ló rọ̀ ká a ní ìhà gúsu, Bájùláyé àti Abúlé Ìjẹṣà ló gbè é ní ìwọ̀ òrùn nígbà tí Yábàá yíì ká ni ìhà àríwá. Abúlé Ọjà wà ní Ìjọba ìdàgbàsókè Yaba (Yaba LCDA) ní Ìpínlẹ̀ Èkó. ÌṢẸ̀WÁ À ti Ìlú Biní ni baba ńlá bàbá àwọn ọmọ àti Oònilẹ̀ Abúlé Ọjà ti ṣẹ̀wá bí ó ti ṣe rí fún púpọ̀ àwọn ìlú tí ó wà ní Èkó. Àbádárìgì, Ẹ̀pẹ́, Ìsàlẹ̀ Èkó jẹ́ pàtàkì lárá àwọn ìlú pàtàkì tí wọ́n jọ tẹ̀dó tí wọ́n sì jẹ iyèkan. BÁÁLẸ̀ JÍJẸ Báálẹ̀ ni oyè tí ó tó bi jù lọ ni Abúlé Ọjà, ọdún 1944 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ oyè báálẹ̀ ni ìlú yìí. Ìdílé Elétù Òdìbò ni ó ń jẹ Báálẹ̀, àwọn sì ni wọ́n ń ṣe àkoso gbogbo ilẹ̀ Abúlé Ọjà àti ìdá kan nínú mẹ́ta ilẹ̀ Abúlé Ìjẹṣà. Báálẹ máa ń ṣe ìjọba pẹ̀lú àwọn àwòrò ǹṣàṣà tí wọ́n jẹ́ àgbà láàrín ìlú. Elétù Òdìbò Èkó ni ó máa ń fi Báálẹ̀ jẹ. Nínú ètò àti ìlàna tí wọ́n fi yan báálẹ̀ tí ó wà lórí àlééfà ni wọ́n tí ṣé lófin pé ẹni tí kò bá ì tíì tó ọmọ àádọ́ta ọdún kò lè jẹ Báálẹ Abúlé Ọjà, èyí tí ó lè ṣe àkóba ńláǹlà fún ètò ìlú náà. Báyìí ni orúkọ àwọn tí wọ́n ti jẹ Báálẹ̀ ṣe lọ, àti àwọn Elétù Òdìbo tí wọ́n fi wọ́n jẹ: Ọdún 1944 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ oyè Báálẹ̀ ní Abúlé Ọja, Olóyè Sèídù Bánkọ́lé ló kọ́kọ́ jẹ ẹ́, Elétǔ Òdìbò (Olóyè) AbduLlahi Bámgbọ́pàá ni ó sì fi wọ́n jẹ. Báàlẹ́ yìí lo sáà wọn títí ọdún 1952 nígbà tí ẹlẹ́mìí gbà á. Fún ọdún márùn ún ni kò fi sí Baálẹ̀ lórí àtẹ́ ní ilú Abúlé Ọjà. Ìgbà tì ó ma fi di ọdún 1957 lẹ́yìn ìgbà tí ẹlòmíì ti jẹ oyè Elétǔ Òdìbò (Olóyè) Ámúsà Gbádéṣeré ti jẹ oyè Elétǔ, wọ́n fi Olóyè Sulaiman Balógun Elétǔ Òdìbò jẹ báálẹ. Báálẹ Sulaiman wà lórí òyè di ọdún 1974 tí ó fi wèwàlẹ̀ àsà, bí ẹ ti mọ̀ pé nílẹ̀ Yorùbá pé ikú nìkan ló lè yẹ Ọba tàbi Báálẹ̀ kúrò lórí oyè. Ó tó ọdún mẹ́wàá dáadáa kí báálẹ míì tún tó jẹ, ọdun 1984 sì ni. Iṣẹ́ ìwádìí fi yé wa pé fún gbogbo ọdun tí kò fi sí Báálẹ̀ lórí ìtẹ́, igbimọ fìdí hẹ́ ni ó ń tukọ̀ ìlú. Olóyè Andrew Ayọ̀délé ló jẹ Báálẹ̀ tí Elétǔ Òdìbò (Olóyè) Ìṣọ̀lá Bájùláyé Gbádéṣeré si fi oyè Báálẹ jẹ. Ọdún 1989 ni Olóyè Andrew ṣípò padà. Ó lé ní ogún ọdún dáadáa kí báálẹ tó wà lórí àlééfa lọ́wọ́lọ́wọ́ tó jẹ, èyíkò ṣàì rí bẹ̀ bí óti jẹ́ pe, ogun ọtẹ ló kó ìlú ní pápá mọ́ra. Ọdún 2013 ni Olóyè M.K.I. Adédèjì Balógun- Eletǔ jẹ Báálẹ̀, Bábá (Olóyè) Tajudeen Agboọlá Elétù Òdìbò ti ilú Èkó ló sì fi wọ́n jẹ. ÌYÀTỌ̀ TÍ Ó WÀ LÁÀRÍN ÍN ELÉTÙ ÒDÌBÒ ÀTI BÁÁLẸ̀ Ìyàtọ̀ kékeré kọ́ ló wà láàárín oyè Elétù Òdìbò àti Báálẹ̀. Bí sánmọ̀ ṣe jìnà si ilẹ̀ tó ni Elétù Òdìbò ṣe jìnà sí Báálẹ̀. Ẹbí tàbi Ìdílé kan náà ni àwọn méjéèjì ti wá ṣùgbọ́n baba ni Elétùú Òdìbò jẹ́ sí Báálẹ̀, Elétùú Òdìbo ní í máa ń yan Báálẹ gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ ní àárín ìlú. Nínú gbogbo àwọn olóyè abìlà funfun t’Èkó, Elétùú Òdìbò ni olórí wọn. Elétùú Òdìbò ló sì máa ń fi Ọba Èkó jẹ, èyí ò ya ni lẹ́nu tìtórí orúkọ ìdílé (Gbádéṣeré) yìí fi hàn bẹ́ẹ̀. Olóyè Tajudeen Agboọlá ni ó wa lóri alèéfà Elétu Òdìbò nígbà tí Olóyè M.K.I. Adédèjì Balógun- Eletu jẹ Báálẹ̀ Abúlé Ọjà. OLÓYÈ M.K.I. ADÉDÈJÌ BALÓGUN- ELETU A bí Báálẹ̀ Abúlé Ọjà ní ǹnkan bi ọdú márùn ún dín lọ́gọ́ta sẹ́yìn sí Ẹbí Elétùù Òdìbò. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ jáde ni ilé ìwé alákọ̀bẹ́rẹ̀ẹ́ ti ‘7th Day Primary School’ tí ó wà ní Abúlé Ọjà, wọ́n tẹ̀ síwájú sí ilé ìwé girama ní Jíbówú High School tí ó ń jẹ́ Premier College, Jíbówú tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ rí. À ì sí owó já wọn ní tàn mọ́ọ̀ láti tẹ̀ síwájú síi. Lẹ́yìn ìwé yìí ni wọ́n lọ kọ́ṣẹ́ ìwé títẹ̀, èyí ni wọ́n ń ṣe títí tí wọ́n fi joye Báálẹ̀ ní ọdún 2013. Ìnágijẹ oyè wọn ni Ìlúfẹ́milóyè I. Báálẹ̀ fẹ́ ìyàwó méjì, Olorì Táwàkálítù Adédèjì Balógun- Elétǔ àti Olorì Ọmọlará Adédèjì Balógun- Elétǔ pẹ̀lụ́ àwọn ọmọ alálùbáríka ORÍKÌ Ọmọ Ẹrin ò béjì Tí ó bá béjì, ọ̀kan á dìso Àwa ló lọwá Àwa ló lọba Elétǔ Òdìbò la fọba jẹ ORÍKÌ- ÌLÚ ORÍKÌ ÌJẸ̀BÚ Ìjẹ̀bú ọmọ alárè Ọmọ Awujálè Ọmọ Arójò Joyè Ọmọ Alágem Ògún Ọmọ Aladìye Ògògòmógà Ọmọ Adìye Bàlókùn Ara Òrokùn Ara ò Radìye Ọmọ Ohun Ṣéní Òyòyò mayòmo ohun ṣéní Olèpani, ỌMỌ dúdú ilé komobe ṣe níjósí Ọmọ moreye mamaroko, morokotan ẹyẹ mátìlo Ọmọ mo ní isunle mamalobe ọbẹ̀ tin be nílé kò mọ ilé baba tó bí wọn lọmọ Ọmọ Onígbò ma’de Ọmọ Onígbò mawo mawo Ọmọ Onígbò ajoji magbodowo Àjòjì tobawo gboro yio di ebora ile baba tobi wan lomo Ìjẹ̀bú ọmọ èrè níwà Ọmọ Olówó Ìṣèmbáyé Òrìsà jẹ́ ń dàbí onílé yí kelebe Ìjẹ̀bú owó Ìtò Ìjẹ̀bú owó Dúdú Ìjẹ̀bú owó Pupa Ìjẹ̀bú owó Kékeré Ìjẹ̀bú owó Àgbà Ìjẹ̀bú owó Ìjẹ̀bú òde Ìjẹ̀bú ni Ìjẹ̀bú Igbó Ìjẹ̀bú ni Ìjẹ̀bú Isara Ìjẹ̀bú ni Ayépé Ìjẹ̀bú Ikorodu Ìjẹ̀bú Ìjẹ̀bú ní ṣe Ìjẹ̀bú Ìpẹru Ìjẹ̀bú Ọmọ oní Ilé ńlá Ìjẹ̀bú Ọmọ aláso ńlá Ìjẹ̀bú ọmọ Alárẹ̀. ÌWÚRE ÌWÚRE ÒWÚRỌ̀ Bí igi kò bá léṣo lórí, ayé kì í ju òkò fún un!!. Bẹ́ẹ̀ bí òsùpá kò bá tàn kárí ayé láti alède ọ̀run Ọmọ aráyé kò ní pókìkí ẹ̀!!. Ìwọ́ ọ̀rẹ́ mi, bí o bá ń bẹ̀rù ọ̀tá; Dàkun máse gba àdúrà ìgbéga nítorí ẹ̀dá kan kò ní gòkè ọlà; Káyé ó máse má a lé ipa rẹ̀!! Àdúrà wa ni wí pé kí a máse subú fún ọ̀tá yọ̀!!! ÀKANLÒ ÈDÈ ÀKANLÒ ÈDÈ APÁ KẸTA 1. Mú ọ̀nà pọ̀n . tẹ̀ síwájú nínú àjò 2. Na pápá bora . sálọ 3. Sọ ojú abẹ níkòó . sọ ohun tó jẹ́òtítọ́ 4. Òkété bóru . ọ̀rọ̀ kọjá àtúnṣe 5. Lódìí ìgbín . dojú rú 6. Gbọ́nmi sí I, omi ò tó o . èdè àìyedè tàbí ìjà láàrí ín ẹni méjì 7. Fi ọ̀bọ lọ (ni) . fi ìwọ̀sí lọ ni 8. Ilẹ̀ ń mì . àṣírí fẹ́ tú 9. Já òwú dítí . ṣe àìgbọràn 10. Fi ìrù fọná . dá ọ̀ràn ÀRÒKỌ DÁÚDÀ JÁLÉ AGBỌ́N Àbúrò Sàká ni Dáúdà jẹ́ ṣùgbọ́n, Kúnlé ni ó jẹ àgbà wọn. Bí Dáúdà ṣe jẹ́ ọmọdé tó yìí, ata ni, kò ṣeé fi sí ojú. Gbogbo eré géle tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kò lè ṣe ni ó máa ń ṣe. Dáúdà ní ìkà nínú púpọ̀. Bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe ń kìlọ̀ fún un tó, ṣe ni ó máa ń wa ọrùn kì, tí ó ń kọ etí ikún sí ohun tí wọ́n ń sọ fún un. Dáúdà ní rọ́bà tí ó máa ń fi pa ẹmọ́ kiri ní ẹ̀yìnkùlé. Bí kò bárí ẹmọ́, ó máa ń ta rọ́bà rẹ̀ lu aláǹgbá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹbọ tó fẹ́ fi í rú. Ó jẹ́ àṣà àwọn ọmọdé wọ̀nyí- Dáúdà, Sàká àti Kúnlé, láti máa lọ ran bàbá wọn lọ́wọ́ nínú oko lẹ́hìn tí wọ́n bá ti ilé ẹ̀kọ́ dé. Dáúdà á tilẹ̀ máa fi rọ́bà rẹ̀ tú ìtẹ́ ẹyẹ tí yóò sì pa ẹyẹkẹ́yẹ tí ó bá rí níbẹ̀. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kò fẹ́ràn ohun tí ó ń ṣe yìí, wọ́n sì máa ń fi ẹjọ́ rẹ̀ sun bàbá wọn. Bàbá wọn náà kò ṣàì máa bá a wí. Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ni wọ́n ń yín àgbàdo sí lọ́dọ̀ Dáúdà. Ní ọjọ́ tí Dáúdà ta rọ́bà fọ́ agbè ẹmu bàbá Sídí ní ọ̀nà oko wọn, bàbá rẹ̀ nà án funfun gbẹ́ru gbẹ́ru. Wọ́n gba rọ́bà rẹ̀, wọ́n fi ọ̀bẹ rẹ́ ẹ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Dáúdà tún bọ́ sọ́jà láti ra rọ́bà mìíràn. Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ó ti ra rọ́bà tuntun, àmọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀mọ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ti sú wọn. Ìyẹn ni kò jẹ́ kí wọ́n sọ fún bàbá wọn mọ́. . Lọ́jọ́ tí ọwọ́ pálábá Dáúdà ségi, ẹnu rẹ̀ kọ ìroyìn. Ní ọ̀sán ọjọ́ yìí, wọ́n ń lọ sí oko, Dáúdà ta ojú kán, ó rí nǹkan náà, ó ń mì dìlọ̀d̀lọ̀, àdán ni ó pè é, ó sún mọ́ ọn dáadáa. Bí ó ṣe ta rọ́bà rẹ̀ pàrà, ilé agbọ́n ló lọ bà. Ilé agbọ́n já lé e lórí; agbọ́n ta á lójú àti nímú. Kò sí ibìkan tí wọ́n dásí ní gbogbo orí rẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ kejì, gbogbo iwájú orí rẹ̀ ti wú kọ́ńdú kọ́ńdú, orí rẹ̀ tóbi tó odì ẹyìn, ọmọ ojú rẹ̀ wọnú. Kòsí ẹni tí yóò rí Dáúdà ní àsìkò yìí tí ìrísí rẹ̀ kò ní pa á lẹ́rìn- ín. Yẹ̀yẹ́ ni àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi i ṣe. Kò kúkú lè lọ sí ilé- ẹ̀kó, ńṣe ni àwọn ẹgbẹ rẹ̀ tí wọ́n gbọ́, wá ń kí I nílé. Kòjọ àwàdà, kò jọ yẹ̀yẹ́ ni wọ́n ń fi í ṣe. . Yẹ̀yẹ́ tí wọ́n ń fi Dáúdà ṣe yìí dùn ún púpọ̀. Ó jẹ ìrora oró agbọ́n náà fún ọjọ́ mẹ́ta kí ara rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀sí wálẹ̀. Ọgbọ́n tí bàbá kọ́ Dáúdà tí kò gbọ́n ni agbọ́n wá kọ́ ọ yìí. Ojú rẹ̀ sì já a pé àìgbọràn kì í bímọ rere. . - Yorùbá Òde Òní ÀRÒKỌ Ọ̀FỌ̀ ṢẸ̀ WÁ NÍNÚ ẸBÍ WA APÁ KEJÌ .... . Ẹ̀gbọ́n mi sọ pé òun tì wá àwọn méjéèjì lọ sí ilé àbúrò rẹ̀, ṣùgbọ́n òun kò bá ẹnìkan ní ilé. Bàbá mi kàn dáhùn pé, ‘Bẹ́ẹ̀ni ara àbúrò òun ni kò dá. Ìyá mi ti fi àkísà nu ojú rẹ̀, ṣùgbọ́n omijé kò í tì í bọ́ ní ojú rẹ̀. Ojú rẹ̀ wá pọ́n wẹ̀ẹ̀ bí ẹrẹ iná. Wọ́n ní kí a lọ sí ẹ̀hìnkùlé, ó rẹ àwọn púpọ̀, àwọn sì fẹ́ lọ sinmi. ‘Ṣé kò sí nkan’ ni èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ḿ bèèrè, ‘Kò sí nkan, ‘ ni wọ́n dáhùn. Ọ̀dẹ̀ ènìyàn pàápàá á ti mọ̀ pé ǹkan ḿ bẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ nkan náà. . Àbúrò mi ń yí kẹ̀kẹ́, ó fi ń pariwo. Ń ṣe ni mo pariwo mọ́ ọn, tí mo ní kó mọ̀ pé òníni ọjọ́ ìsinmi ni àti wí pé àti bàbá àti ìyá wa ni inú wọn kò dùn. Bàbá mi kọjá sí ilé ìwẹ̀, mo ní èrò pé ó lọ tọ̀ ni, ṣùgbọ́n ó pẹ́ kí ó tó jáde, ó ní kí n bu omi fún òun kí òun mú, ṣùgbọ́n kàkà kí ó mu omi náà, ojú ni ó fi bọ́, ó sì dámi lójú pé ó ti sọkún. . Mo bèèrè, mo ni, ‘Bàbá, ṣé kò sí nkan?’ Ó wò mí, ó mú mi lọ́wọ́ d́ní bí ẹni pé kò le dá dúró mọ́. Ó ní, Ìyábọ̀, àbúrò mi tí ẹ̀ ń pè ní Bùrọ̀dá Eréko ni ó ń ṣàìsàn púpọ̀; àwọn oníṣègùn òyìnbó tí ó yẹ̀ ẹ́ wò sọ pé kò dájú pé ó lè yè, nítorí àìsàn ikú ni àìsàn náà. ‘Ṣé kò ì kú,’ ni mo bèèrè, ó sì dámi lóhùn pé, ‘Ko ̀ ì kú.’ Mo ní n ó lọ gbàdúrà kí ó má kǔ. Bàbá mi mi’rí, ó jù mí lọ́wọ́ sílẹ̀, ó sì wọ yàrá rẹ̀ lọ.’ . Mo lọ pe ẹ̀gbọ́n mi, mo sì sọ fún un ohun tí bàbá mi sọ fún mi. Àwa méjèèjì lọ sí yàrá wa, a lọ kúnlẹ̀, a sì gbàdúrà wí pé kí Ọlọ́run dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, kí ó má kǔ. Ó jọ l’ójú mi l’ọ́jọ́ náà pé bí a ṣegbàdúrà tán, ẹ̀gbọ́n wa àgbà kò ní í kú mọ́. Ni mo bá bá eré tèmi lọ, mo sì ti fi ọkàn sí I pé tí ó bá ṣe díẹ̀, ara rẹ̀ yóò yǎ, a ó sì tuńn rí I ní Sátidé tí ó ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. . Gbogbo ènìyàn ń wá kí wa ní ilé wa, àwọn ẹbí bàbá mi ń pòòyì, wọ́n á sọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ayọ̀ ní ojú wọn, ojú wọn kan gógó, kò sì sí ẹni tí ó pariwo sọ̀rọ̀ tàbí tí ó bèèrè óńjẹ lọ́wọ́ ìyá mi gẹ́gẹ́ bí àṣà ènìyàn kan tí ó fi ara mọ́ wa púpọ̀. Bí àlejò èyí bá dé, á ní ‘Ẹ kú aájò o, Olúwa á mú ẹsẹ̀ rẹ̀ padà sí ilé o’. Òmíràn á ní, ‘ Ẹsẹ̀ rẹ̀ ni o máa fi rin padà wálé o, Olúwa kò ní jẹ́ kí á gbọ́ o. A kò ní í sáré wá pè wá o.’ Bẹ́ẹ̀ ni kíkí ń pe kíkí, tí àdúrà ń pe àdúrà níjà. . Bí wọn ti gbìyánjú tó pé kí àwa ọmọdé- ilé mọ nkan kan, ń ṣe ni a mọ̀ pé ayọ̀ sí nínú ilé wa ní ọ̀sẹ̀ náà. Èyí kò sì ṣẹlẹ̀ rí. Ní ọjọ́ tí wọ́n dá ońjẹ tí ìyá mi gbé lọ sí ilé- ìwòsàn padà láìjẹ́ pé ènìyàn fọwọ́kàn àn ni ẹrù ti bà mí, ṣùgbọ́n mo sọ́ ọ́ sí ọkàn mi pe mo sá ti gbàdúrà ná. Bàbá Eréko kò le tí ì kú! Bàbá mi sá ju ú lọ púpọ̀, kò ṣàì tì bí ọmọ! Kò ì tìí tó àsìkò tí yóò kǔ. . Èrò mi ni pé kí ènìyàn tó kú ó ní láti ti gbéyàwó, kí ó sì ti bímọ! Èrò ọmọdé gbáà ni èyí, à ṣé ikú kò mọ ọmọdé, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ àgbà, ẹni ikú bá rí ni ikú ú mú lọ. . O ́tó agogo mẹ́jọ tí wọ́n dá ońjẹ padà yìí ni, a rí alùfáà ìjọ wa, àti alùfáà àdúgbọ̀ wa tí kì í ṣe ti ìjọ wa. Àwọn bíi mẹ́rin mǐran tẹ̀lẹ́ wọn. Wọ́n rí mi lójú ọ̀nà, wọ́n ní kí n lọ pe bàbá àti ìyá mi wá. Mo fi ìjókǒ lọ̀ wọ́n. Nígbà tí ìyá mi ti rí àwọn àlúfáà wọ̀nyí, ń ṣe ni ó bú sẹ́kún, tí ó ń pariwo, tí ó ń jára mọ́lẹ̀. Erù ti lẹ̀ bà mí. Mo lérò pé wọ́n wá gbàdúrà kí ara bàbá wa kékeré yìí yá kíákíá ni, à ṣé wọ́n wá tú ọ̀fọ̀ ikú rẹ̀ ni. . - ÌYÁBỌ̀ ÌTÀN D'ÒWE ENI TÓ LERÚ LÓ LERÙ Ní ìgbà àtijó, Oba olórò kan wà, ó ní oko beere, ó ní ilé nlá púpò, ó ní orò jántirere bákannáà ni erú rè kò mo níwòn. Bí ó ti wá ní dúkìá àti orò tó yìí omo obìnrin kan soso ló bí. Nígbà tí Ojó Oba yìí dalé gbèrégbèré tí ó kíyèsi pé àwon asáájú gàpère rè ti n séwó sí i, ni ó bá pe àwon jèpé eégún tirè (tí wón kángun sí i), ó sàlàyé wí pé láti pínnísín ni Àyìnlá olórí erú òun ti n sin òun tèmítèmí láì rojú tàbí puró Nítorí náà, kí won ó jé kí omobìnrin òun ó mú òkan péré nínú dúkìá òun kí gbogbo ìyókù pátá ó sì jé ti olórí erú òun. Ah! ni gbogbo àwon tí wón gbó òrò òhún se pé; "ènìyàn ti seé féràn erú ju omo bíbí inú rè lo?". Àmó oba fi èpè lé e pé yàjóyàjó nikú eni tí ó bá yí òrò òun padà yóòjé. Lòrò bá di wòmí n wò ó fún gbogbo won. Ojó keta òrò yìí ni oba wàjà. Léyìn gbogbo ètò tí ó ye léyìn ìgbésè oba, wón mú ojó láti pín ogún oba ni ìbámu pèlú àsosílè oba. Nígbà tí ojó ìpíngún pé,Basòrun sàlàyé ohun tí Oba so sílè kí elémìí ó tó gbàá, ó sì ro Adéláyò Omo Oba láti tóka òkan péré nínú dúkìá bàbá rè tí yóò jogún kí àwon ó tó fa gbogbo dúkìá yóòkú fún Àyìnlá olórí erú Oba. Ìrònú dorí Adéláyò kodò lórí ohun tí ó lè tókasí, nígbà tí ó se ó ro àwon àgbà àti olóyè tí ó wà níkàlè láti fún òun láàyè láti ronú lórí ohun tí òun yóò mú. Wón gbà fun béè, wón sì fun ní ojó méje péré. Adéláyò dúpé, ó sì fi ìbànújé kúrò lódò àwon àgbà náà, nígbà tí Àyìnlá n béyin kee nítirè fún ayò pé òun ni òun yóò ni gbogbo dúkìá Oba nígbà tí Adéláyò bá ti mú òkan péré. Òrò wá di;" Omo olórò n sunkún, erú olórò n yò. Adéláyò ò fojú boorun páàpáà lórí ìrònú ohun kan soso tí ó le yàn nínú ògòòrò dúkìá tí baba rè fi sílè. Níkeyín, orí rè gbé e ko àgbà dáadáa kan tí ó làá lóye pé erú tí baba rè fún lógún n gan ni kí ó mú, nípa báyìí gbogbo dúkìá bàbá rè yóò padà di tirè nítorí pé eni tí ó ni erú ni ó ni gbogbo ohun ìní erú; eni tó lerú ló lerù. Láàrin kádijúkálàá, ojó ìpíngún pé, esè gbogbo àwon àgbà sì kò. Àyìnlá n yán apá ká pèlú èrò pé òun yóò di olórò lójó náà, àmó àgbà tí ó kó Adéláyò ti so fún un láti máa fi òye kíyèsí ohun gbogbo. Nígbà tí àsìkò tó fún Adéláyò láti mú òkan péré nínú ògòòrò dúkìá tí baba rè fi sílè, ó kúnlè kí gbogbo àgbà tí wón wà níkàlè ó sì tóka sí olórí erú baba rè gégé bí dúkìá baba òun tí òun mú. Ah! Ko gbogbo àwon àgbà pé níbo ni Adéláyò ti kó irú ogbón tí ó lò. Àyìnlá banújé, ó sì toro ààyè láti kó àwon dúkìá Oba pamó kí ó tó wá máa sin Adéláyò, àmó Basòrun sàlàyé pé kò sí dúkìá kankan tí ó lè fowó kàn mó àyàfi èyí tí olúwa rè tuntun (Omo Oba Adéláyò) bá fún un, Nítorí pé eni tí ó lerú ló ni erù. Láti ìgbà yìí ni ó ti di òwe ìpàsamò fún àwon erú pé; ENI TÓ LERÚ LÓ LERÙ. Àbò mi rèé oooo. E kú ìfé Èdè àti Àsà Yorùbá lára mi o. ÀRÒKỌ Ọ̀FỌ̀ ṢẸ̀ WÁ NÍNÚ ẸBÍ oroyoruba.blogspot.com.ng Mo mọ àbúrò bàbá mi tí mo fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí dáradára. Ó jẹ́ onínúrere, ó sì máa ń bá àwa ọmọdé ṣeré púpọ̀. Bí ó bá wa tí à ń ta òkòtó, yóò bá wa ta á; bí à ń ṣe bojúbojú, á bá wa ṣe é; à ní bí ó ṣe taní-wà- nínú ọgbà náa ni à ń ṣe, yóò bọ́ sínú ọgbs̀ bí ẹni wí pé ���gbẹ́ ni wá. Bẹ́ẹ̀ sìni sánmọ̀ jìnnà sílẹ̀. Bí à ń sọ itàn, yóò sọ ìtàn òmìrán tí ó dùn ju tiwa lọ. Ẹnu rẹ̀ dùn púpọ̀. Tí ó bá sọ ìtàn ìjàpá, tí ó fi oyin sí i, tí olúwa rẹ̀ bá ti gbọ́ ìtàn náà ní ogún ìgbà, ń ṣe ni ó màa dàbí ẹni pé ìtàn titun ni! Ó jẹ́ eléré àwàdà tí ó mọ ohun tí ó máa ń wu ọmọdé, tí ó sì máa ń mú inú ọmọdé dùn. . Kí n tilẹ̀ sọ òtítọ́, inu wa máa ń dùn nígbà kigbà tí ó bá wá lọ. Bàbá wa pàápàá kị̀ í bá wa ṣeré tó ti àbúrò rẹ̀ yìí. Nígbà kan, mo gbọ́ tí ba[ɓ ́ mi ń bá a wí pé eré, àwàdà àti yẹ̀yé ni ó máa fi gbogbo ọjọ́-ayé rẹ̀ ṣe, àti pé ní ọjọ wo ni ó máa huwà àgbàlagbà. Ṣé bí a bá dàgbà tán, à yéé ṣorò bí èwe! Ní ti àwà ọmọdé- ilé, ènìyàn pàtàkì ni ó jẹ́ fún wa, a sì ní ìfẹ́ rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. À ń retí rẹ̀ kí ó wá báwa ṣeré ọjọ́ Sátidé tí ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹlẹ̀ yìí títí di alẹ́. A bi ìyá wa pé a kò tíì rí bàbá wa kékeré l’ọ́jọ́ náà, àti pé a kò mọ kín ni ó ṣe é. Bẹ́ẹ̀ kì í ṣe aláì- má- wǎ ní ọjọ́ Satídé. . Nígbà tí ó di ọjọ́ Ọ̀sẹ̀ ni ìyá wa ní tí a bá ń bọ̀ láti ilé- ìsìn, kí a yà ní ilè rẹ̀, kí a wádĩ kín ni ó ṣe é tí a kò fi rí ní àná, tí a kò sì tún fi rí i ní ilé- ìsìn. Kí a sá ní òun ni mo fi gbogbo àsìkò ṣọ́ láti wò ó bí ó bá wá sí ilé-ìsìn l’ọ́jọ́ náà lọ́hǔ. N kò rí i títí ìsìn fi dé òpin. . Nígbà tí a yà ní ilé rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ àná ni inú kan tí ń dà á láàmú, tí kò gbádùn. Nígbà tí ó di òru tí kò í tíì rí àlàáfíà ni wọ́n ṣe ìpínnu láti gbé e lọ sí ilé ìwòsàn ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì. Kí a má fa ọ̀rọ̀ gùn, òun ìyàwó sì ti yà ní ilé wa láti sọ fún bàbá mi pé ó fẹ́ si àbúrò rẹ̀, ó sì ti lọ sí ilé- oníwòsàn, ṣùgbọ́n òun kò bá wọn nílé. . Àwa pàápàá délé, ṣùgbọ́n ìyá mi àti bàbá mi kò sí ní ilé; wọ́n ti lọ sí ilé- ìsìn mǐràn tí wọ́n pè wọ́n sí. Wọ́n tó dé, wọn kò dé, a retí, retí, wọn kò dé. Óńjẹ ọ̀sán tó jẹ, a ò mà rí wọn o. A wá óńjẹ jẹ, ṣùgbọ́n t’ìjayà t’ìjayà ni. Ẹ̀gbọ́n mi ní kí èmi máa tọ́jú àwọn àbúrò wa, kí òun tún padà lọ sí ilé àbúrò baba mi yìí láti lọ wo àwọn òbí wa. Kò pẹ́ púpọ̀, ó padà dé, ó ní kò sí ẹnìyàn kankan ní ilé títí kan ọmọ- ọ̀dọ̀ wọn. Èyí yà wá lẹ́nu ṣùgbọ́n kínni ọmọ ọdún mẹ́sǎn àti mọ́kànlá lè ṣe ju èyí tí a ti ṣe lọ! A dúró à ń wò, à ń retí, ṣùgbọ́n ọ̀sán tún pọ́n, ó fẹ́rẹ di ìrọ̀lẹ́ kí bàbá àti ìyá wa tó wọlé. N ò rí kí ojú bàbá mi pọ́n, kí ó sì rẹ̀wẹ̀sí báyìí rí. Agbára kákáni ó fi kí wa pé a kú ile. . -Ìyábọ̀ ÀKANLÒ ÈDÈ ÀKANLÒ ÈDÈ APÁ KẸTA ÀKANLÒ ÈDÈ . ÌTUNMỌ̀ 1. Mú ọ̀nà pọ̀n . tẹ̀ síwájú nínú àjò 2. Na pápá bora . sálọ 3. Sọ ojú abẹ níkòó . sọ ohun tó jẹ́òtítọ́ 4. Òkété bóru . ọ̀rọ̀ kọjá àtúnṣe 5. Lódìí ìgbín . dojú rú 6. Gbọ́nmi sí I, omi ò tó o . èdè àìyedè tàbí ìjà láàrí ín ẹni méjì 7. Fi ọ̀bọ lọ (ni) . fi ìwọ̀sí lọ ni 8. Ilẹ̀ ń mì . àṣírí fẹ́ tú 9. Já òwú dítí . ṣe àìgbọràn 10. Fi ìrù fọná . dá ọ̀ràn ÌṢINI L'ÉTÍ OLÉ JÍJÀ ÀTI ÌDIGUNJALÈ. Àkíyèsí mi sí àwùjo fi hàn wí pé púpò nínú àwa ènìyàn àwùjo ni a máa n fún jíja olè àti ìdigunjalè ní Ìtumò kannáà ní èyí tí wón sì yàtò gédégbé sí ara won. IRÚ ÈNÌYÀN WO NI À N PÈ NÍ OLÈ? Olè ni eni tí ó mú/gbé/yo nnkan tí kìí se tirè láìgbàse lówó Olóhun(eni tí ó ni nnkan). Òkan ò jòkan àdàpè ni àwon àgbà máa n fún olè wéwéèwé pèlú ìfojúsun òsunwon ohun tí eni náà gbé àti ònà tí ó gbà gbé e. ÀFOWÓRÁ; èyí ni kí á beni nísé, kí onítòun wá yo sílè nínú owó ohun tí ó ye kí ó rà. Bí àpeere, eni ti wón rán ní ojà egbèfa náírà àmó tí ó ra elégbèrún náìrà fi owó rá igba náírà ni. ÌFÉWÓ; èyí ni kí ènì kí ènìyàn ó rí nnkan tí ó pò nílè, kí ó sì yo níbè. Bí wón bá ní ènìyàn n féwó ohun tí ó túmò sí ni wí pé; bí irú onítòun bá gba ègbé odidi nnkan kojá, nnkan náà yóò di ààbò/ìlàjì. JÀGÙDÀ; Èyí ni eni tí o máa n gbé ohun tí ó bá rí tán làìnáání bí yóò ti dún olóhun sí. Àgbétán ni jàgùdà n gbé erù tí owó rè bá bà. ÀKÍYÈSÍ PÀTÀKÌ Àwon ìsòrí olè métèèta wònyí kìí lo ohun ìjà kankan, àwon gan ni òwe "Ìjànbá solè oníléjí" bámu nítorí pé ó rorún fún Olóhun tí ó bá gbóyà láti mú èyíkéyìí nínú àwon olè wònyí. IRÚ ÈNÌYÀN WO NI ADIGUNJALÈ? Adigunjalè gégé bí orúko rè ni eni tí ó di ìhámóra Ogun lo sí oko olè. Àwon wònyí a máa mú onírúurú ohunèlò Ogun bí ìbon,òkò, àdá, idà, òbe abbl dání lo sí oko olè láti dáàbòbo ara won nítorí ìdágirì bí onílé bá jí àti láti le wón ìlèkùn. Onílé tí ó bá fé se wón ní ìjànbá ni won máa n dojúko àwon yàtò sí àwon agbanipa, kí ipá onílé ó má baà ká won ni wón fi n di ìhámóra Ogun. NÍTORÍ NÁÀ, Gbogbo eni tí ó bá mú,gbé, tàbí yo ohun tí kìí se tirè láìgbàase ni olè nígbàtí adigunjale jé eni tí ó fi ipá gba,mú tàbí gbé ohun tí kìí se tirè. Àbò mi rèé lórí èyí, kÓlódùmarè ó fún mi lókun láti se àwon isé tí ó tún wà níwájú mi. Àmín. E kú ìfé Àsà àti Èdè Yorùbá lára mi o. ORÍKÌ IGÚN Igún, ọmọ ajẹbọ, Lábàlúyẹ̀gẹ̀, ọmọ a-jẹ̀’ gbin-kàsì- má-bì; Igúnnugún tiiri ẹnu gọ́gọ́. Àbàlúyẹ̀gẹ̀, lásán kí ‘Gún ò n’írun lórí. Igún ń’írun lórí, ẹbọ l’ó m’órí Igún Pá kánrin- kése. K’á rúbọ àgùtàn, k’á tún m’ádìẹ ọ̀ṣọ́rí, K’á fi rúbọ s’óríta; Gbogbo a-jí-mú-t’ẹbọ-gbọ́ T’igún ni wọ́n ń ṣe. Igúnnugún tí í jẹun ẹbọ gbé . Òjò gbogbo l’órí akítì ní í dáá lé.. Aró pẹ̀ l’ómi, ó d’òkúṣú, Lábàlúyẹ̀gẹ̀ pẹ́ l’ẹ́bọ, ó d’alákǐsà aṣọ. Iṣẹ́ nṣẹ́ ‘Gún, Àwòdì ò bá ‘Gún ra. Ojú n pọ́n ‘Gún, ẹyẹ- oko ò bá ‘Gún ṣe. . Igún t’orí ẹbọ, ó f’oríta ṣe ‘lé. Lábàlúyẹ̀gẹ̀ t’orí ẹ̀gbin, ó fàkìtàn ṣe yẹ̀wù. Igún l’ẹ́bọ jíjẹ ò ṣe ǹkan, K’ó yí ni lárá nìkan lèèwọ̀. Afínjú ẹyẹ tí I f’àkísà ṣè ‘rọ̀rí ÀKANLÒ ÈDÈ . ÌTUNMỌ̀ 1. Ya akin . jẹ́ alágbára ènìyàn 2. Òkété bóru . ọ̀rọ̀ kọjá àtúnṣe 3. Ru etí ọmọ láńgidi . ṣe àìgbọràn 4. Mú ọ̀nà pọ̀n . tẹ̀ síwájú nínú ìrìn àjò 5. Na pápá bora . sálọ 6. Tu itọ́ sókè fi ojú gbà á . bínú gidigidi 7. Di bárakú . mọ́ ni lára 8. Fẹ́ra kù . lóyún 9. Ruga . hu ìwà ìgbéraga 10. Ológbò inú ọ̀kẹ́ . ohun tó dára níta tí kò dára nínú . MO DI OBÌNRIN Oṣù kẹta lẹ́hìn tí ìyá mi kú ni mo di obinrin. Mo bẹ̀rẹ̀ síi rí ǹkan oṣù mi. Ẹ̀gbọ́n mi ti rí ti ẹ̀ síwájú; ìyá mi sì ti ṣe àlàyé díẹ̀ fún mi nípa rẹ̀. Ẹ̀rù kò bà mí púpọ̀, ṣùgbọ́n ó sì jẹ́ ohun ìyàlẹnu fún mi, ó sì ṣe àjèjì lára mi fún ìwọ̀n ọdún mélǒ kan. . Ìyá mi pèmí sí ìyàrá rẹ̀, ó ní, Ìyábọ̀, o di obìnrin lónǐ o. Ọjọ́ pàtàkì ni ọjọ́ yìí jẹ́ fún ọ, ọjọ́ ayọ̀ sì ni o. Òní ni o mọ̀ pé obìnrin ni ọ́; tí o lè di abiyamọ. O ní láti tọ́jú arà rẹ, kí o má jẹ̌ kí eṣù tán ọ̀ jẹ kí o lọ bá ọkùnrin ṣe eré ìṣekúṣe. Ẹni tí ó bá ti ń rí ǹkan oṣù rẹ̀, tí ó bá bá ọkùnrin ṣ’erékéré, oyún ni yóò ní. Ọmọ ni a gbàdúrà kí a fi oyún bí. . Ǹkan pàtàkì ni oyún, ayọ̀ púpọ̀ sì ni ó ń fún ni tí ènìyàn bá ní oyún ní àsìkò tí ò tọ́, àti àsìkò tí ó yẹ, èyí sí ni lẹ́hìn ìgbéyàwó. Ẹni tí ó bá lọ lóyún, tí ó lọ bímọ, kí ó tó gbé ìyàwó, ó sọ epo di àbàwọ́n nìyẹn. . ‘Ṣé o mọ̀ pé, óúnjẹ ni epo pupa, òhun ni a fi ń se ọbẹ̀, tí a fi ń se óúnjẹ gbogbo. Kò sí ẹni tí kò fẹ́ epo nínú ọbẹ̀, tí kì í rà á ní ọjà, ṣùgbọ́n tí epo bá lọ dà sí aṣọ mímọ́ pàtàkì olúwarẹ̀, kíákíá ni olúwa rẹ̀ yóò lọ fọ̀ ọ́ dànù’. Orí aṣọ wíwọ̀ wa pàtàkì kò ní ilé epo, níto rí náà, fífọ̀ dànù ni a ó fọ̀ ọ́ dànù. Bẹ́ẹ̀ náà ni oyún; tí ènìyàn bá lọ ní in ní àsìkò tí kò dára, ó di epo tí ó dà síni láṣọ nìyẹn, kàkà kí a jẹ óúnjẹ pàtàkì tí a fẹ́, tí ó sì máa ṣe wá ní oore, á di ohun ìbànújẹ́ fún wa. Fi ojú sí ìwé rẹ títí di àkókò tí ìwọ yóò fi rí ọkùnrin tí ó wù ọ́, tí ẹ ó sì ṣe ètò àti gbéyàwó l’ọ́jọ́ iwájú. Bí o bá lọ ní oyún ní àkókò tí o wà ní ilé- ìwé, ìwọ ni yóò pòfo. . ‘Ọkùnrin yóò máa bá iṣẹ́ tàbí ìwé rẹ lọ, ṣùgbọ́n obìnrin parí tirẹ̀ síbẹ̀ nìyẹn o. Èrò burúkú àti ba oyún jẹ́ ni í máa ń wà l’ọ́kàn obìnrin tí ó ní oyún àìròtẹ́lẹ̀. Nítorí náà, Ìyábọ̀, ṣọ́ra rẹ o. O ti di ẹni ẹlẹgẹ́ láti òní lọ. O ti di ẹyìn tí a gbọ́dọ̀ dìmú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ nítorí tí a bá jẹ́ kí o bọ́, tí o sì fọ́, kò ní ṣé kójọ mọ. Jọ̀wọ́ o, Ìyábọ̀, ṣe ọmọ dáadáa o. Ààbọ̀ ọ̀rọ̀ ni à ń sọ fún ọmọlúwàbí, tí ó bá dé inú rẹ̀ á di odidi. . Mo ti dàgbà t́o láti mọ ǹkan tí ìyá mi ń sọ, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ sì dàrú mọ́ mi lórí. Nígbà tí ìyá mi ṣàdúrà fún mi, tí ó sọ gbogbo èyí tí ó níi sọ tán, ṣe ni mo wọ ìyàrá lọ, tí mo lọ sọkún bí ẹni pé ọ̀fọ̀ ṣe mí. . Ìyàlẹnu ni ó jẹ́ fún mi ní ọjọ́ kejì tí bàbá mi pè mí tí ó kí mi, tí ó sì fún mi ní owó fún orííre pé mo di obìnrin, tí ó sì ní kí n mú owó náà fún ìyá mi, kí ó sì fi se óúnjẹ fún mi. N kò tilẹ̀ rántí bí wọ́n se óúnjẹ nígbà ti ẹ̀gbọ́n mi, ṣùgbọ́n ti emi yìí jẹ́ ǹkan tí n kò le gbàgbé. . Ìyá mi ní kí n pe àwọn ọ̀rẹ́ mi wá láti ilé-ìwé wa. Mo ní kín ni n ó sọ fún wọn pé mò ń ṣe. Ìyá mi ní kí n kàn ní ìyá àti bàbá mi fẹ́ ṣe sàráà fún mi. Irọ́ ọjọ́ ìbí kò ṣé e pa nítorí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ni wọ́n mọ ọjọ́ ìbí mi. . Mo sọ fún ọ̀rẹ́ mi kan pé ìyá àti bàbá mi fẹ́ ṣe sàráà fún mi ní ọjọ́ àbámẹ́ta, tí à ń pè ní Sátidé, mò sì fẹ́ kí o wá. Kí n tó sọ̀rọ̀ tán ni ó ní, ‘ Tàbí ìwọ náà ti di obìnrin?’ Mo ní láti jẹ́wọ́ fún un. Ó ní ní oṣù tí ó kọjá ni òun náà rí ti òun tí bàbá àti ìyá òun náà ṣe sàráà fún òun. Èyí jẹ́ kí ara mi fúyẹ́ díẹ̀. Díẹ̀ nínú àwọn tí mo pè mọ ohun tí ó fa sàráà yìí. Àjọ wa ní ọjọ́ Satídé náà si dùn ju bí mo ti ní èrò lọ. . Adìẹ mẹ́ta ni ìyá mi pa, ó sì se ìrẹsì. Ó sì tún ra ọsàn, ìrèké àti ọ̀gẹ̀dẹ̀. ‘Wà á ṣe obìnrin kalẹ́ o. Wà á bí ọkùnrin, bí obìnrin, tí ọjọ́ bá yá o. O kò ní ṣi ilé wọ̀,’ ni ìyá wa àgbà kan kí mi. Èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé ìyá mi ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi fún- un. ÀWỌN ỌBA ALAYÉ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN ORÚKỌ OYÈ ORÚKỌ ÌLÚ 1. Aláké Abẹ́òkúta 2. Ọlọ́tà Ọ̀tà 3. Awùjalẹ̀ Ìjẹ̀bú Òde 4. Orímọlúsì Ìjẹ̀bú Igbó 5. Àkárìgbò Rẹ́mọ 6. Ọdẹmọ Ìṣarà 7. Olú Ìlaròó 8. Aláyé Ayétòrò 9. Olówu Òwu 10. Ọbaládí Afọn 11. Moloda Odògbólú 12. Ológèrè Ògèrè 13. Alápẹ́ru Ìpẹru 14. Ọlọ́fin Ìliṣàn Rẹ́mọ 15. Olúgbolú Ìta Ògbólú 16. Olúbarà Ìbarà(Abẹ́òkúta) 17. Ọlọ́fin Adó Odò (Ẹ̀gbádò) EWÌ ỌMỌDÉ MO BÚ MỌ̀-Ọ́N Mo bú ‘Mọ̀-ọ́n’ Kín ní í jẹ́ ‘Mọ̀-ọ́n’? Mọ̀-ọ́n lóógun; Kín ní í jóógun? Ògún l’Adé; Kin ní í j’Ádé? Adéṣípọ̀; Kin ní í jẹ́ Pò? Pòǹṣẹ́rẹ́; Kin ní í jẹ́ Ṣẹ́rẹ́? Ìṣẹ́rẹ́ Ọmọ́yọ; Kin ní í j’Ọ́mọ́yọ? Ọmọ́yọ Àkókó Kin ní í j’ Àkókó? Àkókó Òrìṣà Kin ní í j’ Òrìṣà? Òrìṣà Alayé; Kin ní í j’ Alayé? Alayé Alọ̀run Alọ̀run Ìgbálá; Kin ní í jẹ Gbàlà? Ìgbálá ìgbásẹ́; Kin ní í jẹ Gbásẹ́? Ìgbásẹ́ Arẹrẹ; Kin ní í j’ Árẹrẹ? Arẹrẹ ń Mògún; Kin ní í jẹ́ Mògún? Mògún Onírè; Kin ní í j’Onírè? Onírè Apàtẹ; Kin ní í j’Apàtẹ? Apàtẹ Ìlẹ̀kẹ̀; Kin ní í jẹ́ lẹ̀kẹ̀? Ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn ẹ sígógó Sín-ín-ìn! ÀRÒKỌ ÌGBẸ̀YÌN OLÈ Bádérù jẹ́ ògbójú ọlọ́ṣà. Ó máa ń jí ọkọ̀ gbẹ, ó sì máa ń fọ́ báńkì pẹ̀lú. Ó ti sọ òlè jíjà di iṣẹ́ àṣejẹ. Kò sí ẹni tó mọ bàbá rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ìyá rẹ̀. ‘Èkó gba olè, ó gba ọ̀lẹ’, bí ọ̀rọ̀ Yorùba. Kòkú sẹ́ni tó lè bèère ibi tí ẹnikẹ́ni ti ṣàn wá ní ìlú Èkó. Bádérù ti dé Èkó, ilẹ̀ ta sí i. Kò sì sí iṣẹ́kan tí àwọn ará àdúgbò mọ̀ ọ́n mọ́. Olè ló ń jà kiri. Gbogbo àwọn ará àdúgbò ni wọ́n ti fura pe olé ni. . Bádérù kò kúkú mọ̀ pé ẹnikẹ́ni ń wo òun. Ẹni tí à ń wò ní áwòsọkun tí ń wo ara rẹ̀ ní àwò- rẹ́riǹ-ín ni Bádérù. Gbogbo àwọn ará àdúgbò ni kìí fẹ́ kí ọmọ àwọn dé sàkání rẹ̀. Won kò fẹ́ kí ó kọ́ àwọn ọmọ wọn ni iṣẹ́ olè jíjà, ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ ti sú wọn. Wọ́n ń retí ọjọ́ tí ọlọ́pàá yóò tẹ̀ ẹ́. . Ìwà àwọn ará àdúgbò yìí kò dènà kí Bádérù ní àwọn ọ̀rẹ́. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ a sì maá bá a ���eré. Ṣùgbọ́n àtòun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni àwọn ènìyàn fi ojú sí lára gẹ́gẹ́ bí ọlọ́ṣà. . Bí ènìyàn bá pàdé Bádérù ní ibi fàájì, yóò rò pé ọlọ́lá kan ni. Ńṣe ni ó máa ń náwó bí ẹlẹ́dà. Àwọn obìrin àsìkò kì í wọ́n lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó lọ́yàyà, ó sì gbajúmọ̀. Bí Bádérù kìí bá ṣe olè, ó yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní “ẹni ayé yẹ”. . Ní ọjọ́ kan ni a gbọ́ pé ọwọ́ tẹ ọlọ́ṣà kan tí ó lọ jí ọkọ̀ àlùfáà ìjọ Ọlọ́run kan gbé. Bádérù ni. Àwọn ọlọ́pàá mú un. Wọ́n gbé e lọ ilé- ẹjọ́. Wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé ó pa aṣọ́gbà tí ń ṣọ́ ilé àlùfáà yìí. Ẹni bá sì pa ènìyàn, pípa ni à á pa á. Adájọ́ dájọ́ ikú fún Bádérù. Báyìị́ ni Bádérù ṣe gbọ́ ọjọ́ ikú rẹ̀. . Àwọn ènìyàn pariwo yèèè. Inú wọn dùn nítorí Bádérù ti ṣọṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láàrin ìlú. Ní ọjọ́ tí wọ́n fi ẹ̀yìn Bádérù ti àgbá, ńṣe ni ìlú ń rọ́ kẹ̀kẹ̀. Gbogbo ayé ló fẹ́ wo ikú ẹ̀sín ti Bádérù máa kú. Èrò pọ̀ tí wọ́n wá wòran rẹ̀. Wọn kò ṣàánú rẹ̀ rárá. Ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ ló ń kéèésú rẹ̀. Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀. Olè jíjà kò yẹ ọmọlúwàbí . -Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá Òde Òní EWÌ ÀGBÀ BÍ ỌMỌDÉ - Ayọ̀ọlá ọmọ Fádèyí Àgbà bí ọmọdé Bí ẹ rí ẹni tó fi ọ̀pá tẹlẹ̀ Tó sọ̀rọ̀ òmùgọ̀ Ọmọdé ni Àgbà kìí sọ̀rọ̀ òmùgọ̀ Bí ẹwá rí abirun funfun lórí T’ó ń fi ewú orí ṣe bí ajunilọ T’ó ń fi ẹsẹ janlẹ̀ kiri l’àdúgbò Òmọdé ni Pẹ̀lẹ́ sùúrù l’àgbà fì ń lò . Omọdé bí àgbà Bí ẹrí ènìyaǹ tó sọ̀rọ̀ àtàtà lẹ́nu Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n, oní làákàyè Bóṣe ọmọdé lójú yín Àgbà ni Bí ẹ rí abirun dúdú lórí Tó sọ̀rọ̀ àtàtà Àgbà ni . Òótọ́ ni Ohun àgbà rí ní ìkàlẹ̀ B’ọ́mọdé ga ọrùn oní- pẹ̀tẹ́ẹ̀sì Kò tó bẹ́ẹ̀, kí ó ri i Àgbà ọjọ́ orí wà Àgbà oní làákàyè ń bẹ . Ṣ’ẹ ri àwọn àgbà ọlọ́jọ́ orí Àwọn ni wọ́n ń mu ẹmu tàkìtì kiri ìlú Àwọn ni kò lè to ilé wọn gún régé Àgbèrè ò fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kan Gbogbo iṣẹ́ ibi, ọwọ́ wọn ló kun mọ Bí a bá dà’gbà, à á yé ogun jà Kọ́ ni ti wọn Wọ́n á so àgbàdo mọ́ ìdí, adìẹ á sì máa lé wọn kiri . ‘Wán tú tírí kọ́ lafi ń mọ àgbà Ó lè ṣe pàtàkì níhà ibìkan Kìí ṣe gbogbo ibi Bí ọmọdé ọlọ́jọ́ orí bá fẹ́ dàgbà onílàákàyè Ó tọ́, kí ó bọ̀wọ̀ fún àgbà ọlọ́jọ́ orí Ó tọ́, kí ó bọ̀wọ̀ fún àgbà onílàákàyè . Wọ́n á pé àádọ́rin ọdún Wọ́n á tún máa lé ọmọọmọ wọn kiri ní àdúgbò Fún fífẹ́ kọ, àgbèrè pọ́nbélé ni Wọ́n á ní ọmo àti aya nílé Ìyà á jẹ ìyàwó àti ọmọ Owó kọ́ ló tán nílé Tàbí iṣẹ́ ló ṣàfẹ́kù Ọtí àti burańdí ló ń dárà Ọtí ti pọ̀jù ọ̀kà wọn lọ Ohun ni aṣọ fi ń pọ́n mọ́ wọn lára . Ẹ̀yin àgbà, ẹ ṣe bí àgbà Ẹ hùwà àgbà Kí ẹ lè ba kó àwọn ọmọ yín jẹ̀ pẹ́pẹ́pẹ́ Ẹnu àgbà ni obì ń gbó sí Kí àwọn ọmọdé, má ba tètè mọ iyì yín . Tani kò fẹ́ d’àgbà tòótó? Tani kò fẹ́ d’àgbà oní làákàyè? Àgbà tí ó mọ ojúṣẹ Kí n má dàgbà ìranù, àgbà ìyà Kí n má dàgbà òṣì, àgbà bí ọmọdé Mo ṣe ìbà àgbà Mo júbà àgbà ARÒKỌ MO DI OBÌNRIN Oṣù kẹta lẹ́hìn tí ìyá mi kú ni mo di obinrin. Mo bẹ̀rẹ̀ síi rí ǹkan oṣù mi. Ẹ̀gbọ́n mi ti rí ti ẹ̀ síwájú; ìyá mi sì ti ṣe àlàyé díẹ̀ fún mi nípa rẹ̀. Ẹ̀rù kò bà mí púpọ̀, ṣùgbọ́n ó sì jẹ́ ohun ìyàlẹnu fún mi, ó sì ṣe àjèjì lára mi fún ìwọ̀n ọdún mélǒ kan. Ìyá mi pèmí sí ìyàrá rẹ̀, ó ní, Ìyábọ̀, o di obìnrin lónǐ o. Ọjọ́ pàtàkì ni ọjọ́ yìí jẹ́ fún ọ, ọjọ́ ayọ̀ sì ni o. Òní ni o mọ̀ pé obìnrin ni ọ́; tí o lè di abiyamọ. O ní láti tọ́jú arà rẹ, kí o má jẹ̌ kí eṣù tán ọ̀ jẹ kí o lọ bá ọkùnrin ṣe eré ìṣekúṣe. Ẹni tí ó bá ti ń rí ǹkan oṣù rẹ̀, tí ó bá bá ọkùnrin ṣ’erékéré, oyún ni yóò ní. Ọmọ ni a gbàdúrà kí a fi oyún bí. Ǹkan pàtàkì ni oyún, ayọ̀ púpọ̀ sì ni ó ń fún ni tí ènìyàn bá ní oyún ní àsìkò tí ò tọ́, àti àsìkò tí ó yẹ, èyí sí ni lẹ́hìn ìgbéyàwó. Ẹni tí ó bá lọ lóyún, tí ó lọ bímọ, kí ó tó gbé ìyàwó, ó sọ epo di àbàwọ́n nìyẹn. ‘Ṣé o mọ̀ pé, óúnjẹ ni epo pupa, òhun ni a fi ń se ọbẹ̀, tí a fi ń se óúnjẹ gbogbo. Kò sí ẹni tí kò fẹ́ epo nínú ọbẹ̀, tí kì í rà á ní ọjà, ṣùgbọ́n tí epo bá lọ dà sí aṣọ mímọ́ pàtàkì olúwarẹ̀, kíákíá ni olúwa rẹ̀ yóò lọ fọ̀ ọ́ dànù’. Orí aṣọ wíwọ̀ wa pàtàkì kò ní ilé epo, níto rí náà, fífọ̀ dànù ni a ó fọ̀ ọ́ dànù. Bẹ́ẹ̀ náà ni oyún; tí ènìyàn bá lọ ní in ní àsìkò tí kò dára, ó di epo tí ó dà síni láṣọ nìyẹn, kàkà kí a jẹ óúnjẹ pàtàkì tí a fẹ́, tí ó sì máa ṣe wá ní oore, á di ohun ìbànújẹ́ fún wa. Fi ojú sí ìwé rẹ títí di àkókò tí ìwọ yóò fi rí ọkùnrin tí ó wù ọ́, tí ẹ ó sì ṣe ètò àti gbéyàwó l’ọ́jọ́ iwájú. Bí o bá lọ ní oyún ní àkókò tí o wà ní ilé- ìwé, ìwọ ni yóò pòfo. ‘Ọkùnrin yóò máa bá iṣẹ́ tàbí ìwé rẹ lọ, ṣùgbọ́n obìnrin parí tirẹ̀ síbẹ̀ nìyẹn o. Èrò burúkú àti ba oyún jẹ́ ni í máa ń wà l’ọ́kàn obìnrin tí ó ní oyún àìròtẹ́lẹ̀. Nítorí náà, Ìyábọ̀, ṣọ́ra rẹ o. O ti di ẹni ẹlẹgẹ́ láti òní lọ. O ti di ẹyìn tí a gbọ́dọ̀ dìmú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ nítorí tí a bá jẹ́ kí o bọ́, tí o sì fọ́, kò ní ṣé kójọ mọ. Jọ̀wọ́ o, Ìyábọ̀, ṣe ọmọ dáadáa o. Ààbọ̀ ọ̀rọ̀ ni à ń sọ fún ọmọlúwàbí, tí ó bá dé inú rẹ̀ á di odidi. Mo ti dàgbà t́o láti mọ ǹkan tí ìyá mi ń sọ, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ sì dàrú mọ́ mi lórí. Nígbà tí ìyá mi ṣàdúrà fún mi, tí ó sọ gbogbo èyí tí ó níi sọ tán, ṣe ni mo wọ ìyàrá lọ, tí mo lọ sọkún bí ẹni pé ọ̀fọ̀ ṣe mí. Ìyàlẹnu ni ó jẹ́ fún mi ní ọjọ́ kejì tí bàbá mi pè mí tí ó kí mi, tí ó sì fún mi ní owó fún orííre pé mo di obìnrin, tí ó sì ní kí n mú owó náà fún ìyá mi, kí ó sì fi se óúnjẹ fún mi. N kò tilẹ̀ rántí bí wọ́n se óúnjẹ nígbà ti ẹ̀gbọ́n mi, ṣùgbọ́n ti emi yìí jẹ́ ǹkan tí n kò le gbàgbé. Ìyá mi ní kí n pe àwọn ọ̀rẹ́ mi wá láti ilé-ìwé wa. Mo ní kín ni n ó sọ fún wọn pé mò ń ṣe. Ìyá mi ní kí n kàn ní ìyá àti bàbá mi fẹ́ ṣe sàráà fún mi. Irọ́ ọjọ́ ìbí kò ṣé e pa nítorí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ni wọ́n mọ ọjọ́ ìbí mi. Mo sọ fún ọ̀rẹ́ mi kan pé ìyá àti bàbá mi fẹ́ ṣe sàráà fún mi ní ọjọ́ àbámẹ́ta, tí à ń pè ní Sátidé, mò sì fẹ́ kí o wá. Kí n tó sọ̀rọ̀ tán ni ó ní, ‘ Tàbí ìwọ náà ti di obìnrin?’ Mo ní láti jẹ́wọ́ fún un. Ó ní ní oṣù tí ó kọjá ni òun náà rí ti òun tí bàbá àti ìyá òun náà ṣe sàráà fún òun. Èyí jẹ́ kí ara mi fúyẹ́ díẹ̀. Díẹ̀ nínú àwọn tí mo pè mọ ohun tí ó fa sàráà yìí. Àjọ wa ní ọjọ́ Satídé náà si dùn ju bí mo ti ní èrò lọ. Adìẹ mẹ́ta ni ìyá mi pa, ó sì se ìrẹsì. Ó sì tún ra ọsàn, ìrèké àti ọ̀gẹ̀dẹ̀. ‘Wà á ṣe obìnrin kalẹ́ o. Wà á bí ọkùnrin, bí obìnrin, tí ọjọ́ bá yá o. O kò ní ṣi ilé wọ̀,’ ni ìyá wa àgbà kan kí mi. Èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé ìyá mi ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi fún- un. ORÍKÌ Ẹ̀GẸ́ (Gbágùúdá) Láfún- yinrin òrimọ́kàle, Igi gogoro ti í kosũ ni ààlà Ẹni t’ó roko, roko, T́ ò gbin ẹ̀gẹ́ l’ó jẹ̀bi ebi t’ó n pa ni. . Láàleè, atiiri apẹ Ò- gbé- kọ̀nkọ̀ṣọ̀- fọhùn - ọmọge; A wí pé, ‘Ṣe é mi, ṣe é mi wàyí ṣá! ‘Ṣe é mi, ṣe é mi wàyí ṣá!’ Èdè Yorùbá tí ó rẹwà Ìṣsọ̀kan Ìṣsọ̀kan dára, Eje kí Ìṣsọ̀kan jọba láàrin wa, Ibi tí Ìṣsọ̀kan bá wà, Ìfẹ́, ayọ̀ ìdùnnú àti ifọkanbalẹ kò ní jina sí bẹ, Eje ká ní Ìṣọ̀kan ni ìlú wa, agbègbè wa àti àdúgbò wa pẹ̀lú èyí Ìṣọ̀kan yoo le wà láàrin àwa Yorùbá, Haúsá ibo Àti gbogbo àwọn ẹ̀yà tí o so gbogbo orílẹ̀ èdè Nàìjíríà papọ ni èyí tí yóò je ki agbe ìgbẹ́ ayò àti àlàáfíà laarin ara wa.... EWÌ (ÌKÍNNÍ) IKÚ TÍ YÓÒ PAMÍ - Ayọ̀ọlá ọmọ Fádèyí Ikú tí yóò pamí,kìí ṣe ti Ẹ̀bólà Ikú tí yóò pamí, kìí ṣe tòṣì Ikú tí yóò pamí, kìí ṣe ti ‘HIV’ Ikú tí yóò pamí, kìí ṣe t’ọfà Ìgbà tí mi ò kọhùn Ọlọ́run . Ikú tí yóò pa ọmọ Ádámọ̀ Ń bẹ lára rẹ Ń bẹ ní gbègbèri rẹ Èmi ò ní báwọn kú pipìpi bí adìyẹ Ikú akọni ni n ó kùú . Bí wọ́n pé ọgbọ̀n kú, n ò ní sí nínú wọn Bí wọ́n pé ẹgbẹ̀rún kú, n ò ní sí láàrín- ín wọn Ẹ̀ẹ̀kan n l’ọ́kan ni n ó kú Ikú kan, ọkùnrin kan Ọ̀nà ọ̀fun, kọ́ ni ọ̀nà ọ̀run t’èmi . K’ákú sí ogun ṣàgbà kí wọ́n múni l’ẹ́rú Ọba yóò kú, ẹrú rẹ̀ yóò r’ọ̀run Ọ̀nà ikú yóò gbà l’óṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Ẹrú tí ò kú, á sin olówó rẹ̀ kú Ìwọ̀fà tí ò rọ̀run, á sin olówó rẹ̀ kú . Ikú tí yóò pamí, ìṣòdodo Ikú tí yóò pamí, Ẹ̀sìn Ọlọ́run Ikú tí yóò pamí, ikú ire Ikú tí yóò pamí, Ẹ̀sìn Àláfíà Àìkú s’ógun mi, iná laa lẹ́yìn ọ̀tá Òrò ìsíjú fun ÒròYorùbá Òrò Yorùbá dé, kí eku ilé gbó, kó so fún t'oko, kí àdán gbo, kó rò fún òòbè. Òrò Yorùbá: fún ìgbé láruge èdè, ìse, àsà àti lítírésò Yorùbá. \ No newline at end of file